Ní ìbẹ̀rẹ̀, nígbà tí Ọlọrun dá ọ̀run ati ayé, ayé rí júujùu, ó sì ṣófo. Ibú omi bo gbogbo ayé, gbogbo rẹ̀ ṣókùnkùn biribiri, ẹ̀mí Ọlọrun sì ń rábàbà lójú omi. Ọlọrun pàṣẹ pé kí ìmọ́lẹ̀ wà, ìmọ́lẹ̀ sì wà. Ọlọrun wò ó, ó rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì yà á kúrò lára òkùnkùn. Ó sọ ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán, ó sì sọ òkùnkùn ní òru. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kinni. Ọlọrun pàṣẹ pé kí awọsanma wà láàrin omi, kí ó pín omi sí ọ̀nà meji, kí ó sì jẹ́ ààlà láàrin omi tí ó wà lókè awọsanma náà ati èyí tí ó wà ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ọlọrun dá awọsanma, ó fi ya omi tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ kúrò lára èyí tí ó wà lókè rẹ̀, ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ọlọrun sọ awọsanma náà ní ojú ọ̀run. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ keji. Ọlọrun pàṣẹ pé kí omi tí ó wà lábẹ́ ọ̀run wọ́jọ pọ̀ sí ojú kan, kí ìyàngbẹ ilẹ̀ lè farahàn, ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ó sọ ìyàngbẹ ilẹ̀ náà ní ilẹ̀, ó sì sọ omi tí ó wọ́jọ pọ̀ ní òkun. Ó wò ó, ó sì rí i pé ó dára. Ọlọrun pàṣẹ pé kí ilẹ̀ hu koríko jáde oríṣìíríṣìí ohun ọ̀gbìn ati ewéko tí ń so ati oríṣìíríṣìí igi eléso tí ń so èso tí ó ní irúgbìn ninu, ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ilẹ̀ bá hu koríko jáde, oríṣìíríṣìí ohun ọ̀gbìn ati ewéko tí ń so ati oríṣìíríṣìí igi eléso tí ó ní irúgbìn ninu. Ọlọrun wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kẹta. Ọlọrun pàṣẹ pé kí àwọn ìmọ́lẹ̀ wà ní ojú ọ̀run, láti fi ààlà sí ààrin ọ̀sán ati òru, kí wọ́n wà láti jẹ́ àmì, ati láti máa fi àkókò àjọ̀dún, ọjọ́, ati ọdún hàn, kí wọ́n sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ní ojú ọ̀run láti máa tàn sórí ilẹ̀ ayé, ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ọlọrun dá ìmọ́lẹ̀ ńlá meji: ó dá oòrùn láti máa jọba ọ̀sán, ati òṣùpá láti máa jọba òru, ó sì dá àwọn ìràwọ̀ pẹlu. Ọlọrun fi wọ́n sí ojú ọ̀run láti máa tan ìmọ́lẹ̀ sórí ilẹ̀ ayé, láti máa jọba lórí ọ̀sán ati òru, ati láti fi ààlà sí ààrin ìmọ́lẹ̀ ati òkùnkùn. Ọlọrun wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kẹrin. Ọlọrun pàṣẹ pé kí omi kún fún oríṣìíríṣìí ẹ̀dá alààyè, kí ojú ọ̀run sì kún fún àwọn ẹyẹ. Ó dá àwọn ẹranko ńláńlá inú omi ati oríṣìíríṣìí ẹ̀dá alààyè tí ń gbé inú omi, ati oríṣìíríṣìí ẹyẹ. Ọlọrun wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára. Ọlọrun súre fún wọn, ó ní, “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ sì máa pọ̀ sí i, kí ẹ kún gbogbo inú omi òkun, kí àwọn ẹyẹ náà sì máa pọ̀ sí i lórí ilẹ̀.” Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ karun-un. Ọlọrun pàṣẹ pé kí ilẹ̀ mú oríṣìíríṣìí ẹ̀dá alààyè jáde: oríṣìíríṣìí ẹran ọ̀sìn, oríṣìíríṣìí ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀ ati oríṣìíríṣìí ẹranko ìgbẹ́, ó sì rí bẹ́ẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun dá gbogbo wọn, ó wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára. Lẹ́yìn náà Ọlọrun wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á dá eniyan ní àwòrán ara wa, kí ó rí bíi wa, kí wọ́n ní àṣẹ lórí àwọn ẹja inú òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run, àwọn ẹranko ati lórí gbogbo ayé ati àwọn ohun tí wọn ń fàyà fà lórí ilẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun dá eniyan ní àwòrán ara rẹ̀. Takọ-tabo ni ó dá wọn. Ó súre fún wọn, ó ní, “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ máa pọ̀ sí i, kí ẹ kún gbogbo ayé. Kí ayé wà ní ìkáwọ́ yín, kí ẹ ní àṣẹ lórí àwọn ẹja inú omi, lórí ẹyẹ ojú ọ̀run, ati lórí gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ ayé.” Ọlọrun tún wí pé, “Mo ti pèsè gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ń so èso ati igi tí ń so èso tí ó ní irúgbìn ninu fún yín láti jẹ. Bẹ́ẹ̀ ni mo sì ti pèsè àwọn ewéko fún oúnjẹ àwọn ẹranko, ati àwọn ẹyẹ, ati àwọn ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀, ati gbogbo ẹ̀dá alààyè.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ọlọrun wo gbogbo ohun tí ó dá, ó sì rí i pé wọ́n dára. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kẹfa. Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun ṣe parí dídá ọ̀run ati ayé, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn. Ní ọjọ́ keje, Ọlọrun parí iṣẹ́ ìṣẹ̀dá tí ó ti ń ṣe, ó sì sinmi ní ọjọ́ náà. Ó súre fún ọjọ́ keje yìí, ó sì yà á sí mímọ́, nítorí pé ọjọ́ náà ni ó sinmi ninu gbogbo iṣẹ́ ìṣẹ̀dá tí ó ti ń ṣe bọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun ṣe dá ọ̀run ati ayé. Nígbà tí OLUWA Ọlọrun dá ọ̀run ati ayé, kò tíì sí ohun ọ̀gbìn kankan lórí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ewéko kankan kò tíì hù jáde nítorí pé OLUWA Ọlọrun kò tíì rọ òjò sórí ilẹ̀, kò sì tíì sí eniyan láyé tí yóo máa ro ilẹ̀. Ṣugbọn omi kan a máa ru jáde láti inú ilẹ̀ láti mú kí gbogbo ilẹ̀ rin. Nígbà náà ni OLUWA Ọlọrun bù ninu erùpẹ̀ ilẹ̀, ó fi mọ eniyan. Ó mí èémí ìyè sí ihò imú rẹ̀, eniyan sì di ẹ̀dá alààyè. OLUWA Ọlọrun ṣe ọgbà kan sí Edẹni, ní ìhà ìlà oòrùn, ó fi eniyan tí ó mọ sinu rẹ̀. Láti inú ilẹ̀ ni OLUWA Ọlọrun ti mú kí oríṣìíríṣìí igi hù jáde ninu ọgbà náà, tí wọ́n dùn ún wò, tí wọ́n sì dára fún jíjẹ. Igi ìyè wà láàrin ọgbà náà, ati igi ìmọ̀ ibi ati ire. Odò kan ṣàn jáde láti inú ọgbà Edẹni tí omi rẹ̀ máa ń mú kí ọgbà náà rin. Lẹ́yìn tí odò yìí ṣàn kọjá ọgbà Edẹni, ó pín sí mẹrin. Orúkọ odò kinni ni Piṣoni. Òun ni ó ṣàn yí gbogbo ilẹ̀ Hafila ká, níbi tí wúrà wà. Wúrà ilẹ̀ náà dára. Turari olówó iyebíye tí wọ́n ń pè ní bedeliumu, ati òkúta olówó iyebíye tí wọ́n ń pè ní onikisi wà níbẹ̀ pẹlu. Orúkọ odò keji ni Gihoni, òun ni ó ṣàn yí gbogbo ilẹ̀ Kuṣi ká. Orúkọ odò kẹta ni Tigirisi, òun ni ó ṣàn lọ sí apá ìlà oòrùn Asiria. Ẹkẹrin ni odò Yufurate. OLUWA Ọlọrun fi ọkunrin tí ó dá sinu ọgbà Edẹni, kí ó máa ro ó, kí ó sì máa tọ́jú rẹ̀. Ó pàṣẹ fún ọkunrin náà, ó ní, “O lè jẹ ninu èso gbogbo igi tí ó wà ninu ọgbà yìí, ṣugbọn o kò gbọdọ̀ jẹ ninu èso igi ìmọ̀ ibi ati ire. Ọjọ́ tí o bá jẹ ẹ́ ni o óo kú.” Lẹ́yìn náà OLUWA Ọlọrun sọ pé, “Kò dára kí ọkunrin náà nìkan dá wà, n óo ṣe olùrànlọ́wọ́ kan fún un, tí yóo dàbí rẹ̀.” Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun bu erùpẹ̀ ilẹ̀, ó fi mọ gbogbo ẹranko ati gbogbo ẹyẹ. Ó kó wọn tọ ọkunrin náà wá, láti mọ orúkọ tí yóo sọ olukuluku wọn. Orúkọ tí ó sì sọ wọ́n ni wọ́n ń jẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni ọkunrin náà sọ gbogbo ẹran ọ̀sìn ati gbogbo ẹyẹ ati ẹranko ní orúkọ, ṣugbọn ninu gbogbo wọn, kò sí ọ̀kan tí ó le jẹ́ olùrànlọ́wọ́ tí ó yẹ ẹ́. Nígbà náà OLUWA Ọlọrun kun ọkunrin yìí ní oorun àsùnwọra, nígbà tí ó sùn, Ọlọrun yọ ọ̀kan ninu àwọn egungun ìhà rẹ̀, ó sì fi ẹran dípò rẹ̀. Ó fi egungun náà mọ obinrin kan, ó sì mú un tọ ọkunrin náà lọ. Ọkunrin náà bá wí pé, “Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ rí ẹni tí ó dàbí mi, ẹni tí a mú jáde láti inú egungun ati ẹran ara mi; obinrin ni yóo máa jẹ́, nítorí pé láti ara ọkunrin ni a ti mú un jáde.” Ìdí nìyí tí ọkunrin yóo ṣe fi baba ati ìyá rẹ̀ sílẹ̀, tí yóo sì faramọ́ aya rẹ̀, àwọn mejeeji yóo sì di ara kan ṣoṣo. Ọkunrin náà ati obinrin náà wà ní ìhòòhò, ojú kò sì tì wọ́n. Ejò jẹ́ alárèékérekè ju gbogbo ẹranko tí OLUWA Ọlọrun dá lọ. Ejò bi obinrin náà pé, “Ngbọ́! Ṣé nítòótọ́ ni Ọlọrun sọ pé ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ninu èso àwọn igi ọgbà yìí?” Obinrin náà dá a lóhùn, ó ní: “A lè jẹ ninu èso àwọn igi tí wọ́n wà ninu ọgbà, àfi igi tí ó wà láàrin ọgbà nìkan ni Ọlọrun ní a kò gbọdọ̀ jẹ ninu èso rẹ̀, a kò tilẹ̀ gbọdọ̀ fọwọ́ kàn án, ati pé ọjọ́ tí a bá fọwọ́ kàn án ni a óo kú.” Ṣugbọn ejò náà dáhùn, ó ní, “Ẹ kò ní kú rárá, Ọlọrun sọ bẹ́ẹ̀ nítorí ó mọ̀ pé bí ẹ bá jẹ ẹ́, ojú yín yóo là, ẹ óo sì dàbí òun alára, ẹ óo mọ ire yàtọ̀ sí ibi.” Nígbà tí obinrin yìí ṣe akiyesi pé èso igi náà dára fún jíjẹ ati pé ó dùn ún wò, ó sì wòye bí yóo ti dára tó láti jẹ́ ọlọ́gbọ́n, ó mú ninu èso igi náà, ó jẹ ẹ́. Lẹ́yìn náà, ó fún ọkọ rẹ̀, ọkọ rẹ̀ náà sì jẹ ẹ́. Ojú àwọn mejeeji bá là, wọ́n sì mọ̀ pé ìhòòhò ni àwọn wà, wọ́n bá gán ewé ọ̀pọ̀tọ́ pọ̀, wọ́n sán an mọ́ ìdí. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, wọ́n gbúròó OLUWA Ọlọrun tí ń rìn ninu ọgbà. Wọ́n bá sá pamọ́ sí ààrin àwọn igi ọgbà. Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun pe ọkunrin náà, ó bi í pé, “Níbo ni o wà?” Ó dá Ọlọrun lóhùn, ó ní, “Nígbà tí mo gbúròó rẹ ninu ọgbà, ẹ̀rù bà mí, mo bá farapamọ́ nítorí pé ìhòòhò ni mo wà.” Ọlọrun bi í pé, “Ta ló sọ fún ọ pé ìhòòhò ni o wà? Àbí o ti jẹ ninu èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé o kò gbọdọ̀ jẹ?” Ọkunrin náà dáhùn, ó ní, “Obinrin tí o fi tì mí ni ó fún mi ninu èso igi náà, mo sì jẹ ẹ́.” OLUWA Ọlọrun bi obinrin náà pé, “Irú kí ni o dánwò yìí?” Obinrin náà dáhùn, ó ní, “Ejò ni ó tàn mí tí mo fi jẹ ẹ́.” OLUWA Ọlọrun bá sọ fún ejò náà pé, “Nítorí ohun tí o ṣe yìí, o di ẹni ìfibú jùlọ láàrin gbogbo àwọn ẹran ọ̀sìn ati àwọn ẹranko. Àyà rẹ ni o óo máa fi wọ́ káàkiri, erùpẹ̀ ni o óo sì máa jẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. N óo dá ọ̀tá sí ààrin ìwọ ati obinrin náà, ati sí ààrin atọmọdọmọ rẹ ati atọmọdọmọ rẹ̀. Wọn óo máa fọ́ ọ lórí, ìwọ náà óo sì máa bù wọ́n ní gìgísẹ̀ jẹ.” Lẹ́yìn náà Ọlọrun wí fún obinrin náà pé, “N óo fi kún ìnira rẹ nígbà tí o bá lóyún, ninu ìrora ni o óo máa bímọ. Sibẹsibẹ, lọ́dọ̀ ọkọ rẹ ni ìfẹ́ rẹ yóo máa fà sí, òun ni yóo sì máa ṣe olórí rẹ.” Ó sọ fún Adamu, pé, “Nítorí pé o gba ohun tí aya rẹ wí fún ọ, o sì jẹ ninu èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé o kò gbọdọ̀ jẹ, mo fi ilẹ̀ gégùn-ún títí lae nítorí rẹ. Pẹlu ìnira ni o óo máa mú oúnjẹ jáde láti inú ilẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. Ẹ̀gún ati òṣùṣú ni ilẹ̀ yóo máa hù jáde fún ọ, ewéko ni o óo sì máa jẹ. Iṣẹ́ àṣelàágùn ni o óo máa ṣe, kí o tó rí oúnjẹ jẹ, títí tí o óo fi pada sí ilẹ̀, nítorí inú rẹ̀ ni a ti mú ọ wá. Erùpẹ̀ ni ọ́, o óo sì pada di erùpẹ̀.” Adamu sọ iyawo rẹ̀ ní Efa, nítorí pé òun ni ìyá gbogbo eniyan. OLUWA Ọlọrun fi awọ ẹranko rán aṣọ fún Adamu ati iyawo rẹ̀, ó sì fi wọ̀ wọ́n. Lẹ́yìn náà, OLUWA Ọlọrun wí pé, “Nisinsinyii tí ọkunrin náà ti dàbí wa, tí ó sì ti mọ ire yàtọ̀ sí ibi, kí ó má lọ mú ninu èso igi ìyè, kí ó jẹ ẹ́, kí ó sì wà láàyè títí lae.” Nítorí náà OLUWA Ọlọrun lé e jáde kúrò ninu ọgbà Edẹni, kí ó lọ máa ro ilẹ̀, ninu èyí tí Ọlọrun ti mú un jáde. Ó lé e jáde, ó sì fi Kerubu kan sí ìhà ìlà oòrùn ọgbà náà láti máa ṣọ́ ọ̀nà tí ó lọ sí ibi igi ìyè náà, pẹlu idà oníná tí ń jò bùlà bùlà, tí ó sì ń yí síhìn-ín sọ́hùn-ún. Nígbà tí ó yá, Adamu bá Efa, aya rẹ̀, lòpọ̀, ó lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan. Ó ní, “Pẹlu ìrànlọ́wọ́ OLUWA, mo ní ọmọkunrin kan,” ó sọ ọmọ náà ní Kaini. Lẹ́yìn náà, ó bí ọmọkunrin mìíràn, ó sọ ọ́ ní Abeli. Iṣẹ́ darandaran ni Abeli ń ṣe, Kaini sì jẹ́ àgbẹ̀. Nígbà tí ó yá, Kaini mú ninu èso oko rẹ̀, ó fi rúbọ sí OLUWA. Abeli náà mú àkọ́bí ọ̀kan ninu àwọn aguntan rẹ̀, ó pa á, ó sì fi ibi tí ó lọ́ràá, tí ó dára jùlọ lára rẹ̀ rúbọ sí OLUWA. Inú OLUWA dùn sí Abeli, ó sì gba ẹbọ rẹ̀, ṣugbọn inú Ọlọrun kò dùn sí Kaini, kò sì gba ẹbọ rẹ̀. Inú bí Kaini, ó sì fa ojú ro. OLUWA bá bi Kaini, ó ní, “Kí ló dé tí ò ń bínú, tí o sì fa ojú ro? Bó bá jẹ́ pé o ṣe rere ni, ara rẹ ìbá yá gágá, ẹbọ rẹ yóo sì jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà. Ṣugbọn nítorí pé ibi ni o ṣe, ẹ̀ṣẹ̀ ba dè ọ́ lẹ́nu ọ̀nà rẹ, ó fẹ́ jọba lé ọ lórí ṣugbọn tìrẹ ni láti ṣẹgun rẹ̀.” Nígbà tí ó yá, Kaini pe Abeli lọ sinu oko. Nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, Kaini dìde sí Abeli àbúrò rẹ̀, ó sì lù ú pa. OLUWA bá pe Kaini, ó bi í pé, “Níbo ni Abeli, àbúrò rẹ wà?” Ó dáhùn, ó ní, “N kò mọ̀. Ṣé èmi wá jẹ́ bí olùṣọ́ àbúrò mi ni?” OLUWA bá bi í pé “Kí ni o dánwò yìí? Láti inú ilẹ̀ ni ẹ̀jẹ̀ àbúrò rẹ ti ń kígbe pè mí. Wò ó! mo fi ọ́ gégùn-ún lórí ilẹ̀ tí ó mu ẹ̀jẹ̀ arakunrin rẹ tí o pa. Láti òní lọ, nígbà tí o bá dá oko, ilẹ̀ kò ní fi gbogbo agbára rẹ̀ so èso fún ọ mọ́, ìsáǹsá ati alárìnká ni o óo sì jẹ́ lórí ilẹ̀ ayé.” Kaini dá OLUWA lóhùn, ó ní, “Ìjìyà yìí ti pọ̀jù fún mi. O lé mi kúrò lórí ilẹ̀, ati kúrò níwájú rẹ, n óo sì di ìsáǹsá ati alárìnká lórí ilẹ̀ ayé, nígbà tí ó bá yá, ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi ni yóo pa mí.” Ṣugbọn OLUWA dáhùn, ó ní, “Rárá o! ẹnikẹ́ni tí ó bá pa Kaini, a óo gbẹ̀san lára rẹ̀ nígbà meje.” Nítorí náà OLUWA fi àmì sí ara Kaini kí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí i má baà pa á. Kaini bá kúrò níwájú OLUWA, ó lọ ń gbé ìlú tí ń jẹ́ Nodu. Ó wà ní apá ìlà oòrùn ọgbà Edẹni. Kaini bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó lóyún, ó sì bí Enọku. Kaini lọ tẹ ìlú kan dó, ó sọ ìlú náà ní Enọku, tí í ṣe orúkọ ọmọ rẹ̀. Enọku bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọ́ ní Iradi. Iradi bí Mehujaeli, Mehujaeli bí Metuṣaeli, Metuṣaeli bí Lamẹki. Lamẹki fẹ́ iyawo meji, ọ̀kan ń jẹ́ Ada, ekeji ń jẹ́ Sila. Ada ni ó bí Jabali, tíí ṣe baba ńlá gbogbo àwọn tí wọn ń gbé inú àgọ́, tí wọ́n sì ń sin ẹran ọ̀sìn. Orúkọ arakunrin rẹ̀ ni Jubali, òun ni baba ńlá gbogbo àwọn tí wọn ń lu hapu ati àwọn tí wọn ń fọn fèrè. Sila bí Tubali Kaini. Tubali Kaini yìí ni baba ńlá gbogbo àwọn alágbẹ̀dẹ tí ń rọ ohun èlò irin, ati idẹ. Arabinrin Tubali Kaini ni Naama. Nígbà tí ó yá Lamẹki pe àwọn aya rẹ̀, ó ní: “Ada ati Sila, ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ẹ̀yin aya mi, ẹ gbọ́ mi ní àgbọ́yé: Mo pa ọkunrin kan nítorí pé ó pa mí lára, mo gba ẹ̀mí eniyan nítorí pé ó ṣá mi lọ́gbẹ́. Bí ẹ̀san ti Kaini bá jẹ́ ẹ̀mí eniyan meje, ẹ̀san ti Lamẹki gbọdọ̀ jẹ́ aadọrin ẹ̀mí ó lé meje.” Adamu tún bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan. Ó sọ ọ́ ní Seti, ó ní: “Ọlọrun tún fún mi ní ọmọ mìíràn dípò Abeli tí Kaini pa.” Seti bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọ́ ní Enọṣi. Nígbà náà ni àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí jọ́sìn ní orúkọ mímọ́ OLUWA. Àkọsílẹ̀ ìran Adamu nìyí: Nígbà tí Ọlọrun dá eniyan, ó dá wọn ní àwòrán ara rẹ̀. Takọ-tabo ni ó dá wọn, ó súre fún wọn, ó sì sọ wọ́n ní eniyan. Nígbà tí Adamu di ẹni aadoje (130) ọdún, ó bí ọmọkunrin kan. Ọmọ náà jọ ọ́ gidigidi, bí Adamu ti rí gan-an ni ọmọ náà rí. Ó bá sọ ọ́ ní Seti. Lẹ́yìn tí ó bí Seti, ó tún gbé ẹgbẹrin (800) ọdún láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. Gbogbo ọdún tí Adamu gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé ọgbọ̀n (930), kí ó tó kú. Nígbà tí Seti di ẹni ọdún marundinlaadọfa (105), ó bí Enọṣi. Lẹ́yìn tí ó bí Enọṣi, ó tún gbé ẹgbẹrin ọdún ó lé meje (807) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. Gbogbo ọdún tí Seti gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé mejila (912), kí ó tó kú. Nígbà tí Enọṣi di ẹni aadọrun-un ọdún, ó bí Kenani. Lẹ́yìn tí ó bí Kenani, ó gbé ẹgbẹrin ọdún ó lé mẹẹdogun (815) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. Gbogbo ọdún tí Enọṣi gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé marun-un (905) kí ó tó kú. Nígbà tí Kenani di ẹni aadọrin ọdún, ó bí Mahalaleli. Lẹ́yìn tí ó bí Mahalaleli, ó gbé ẹgbẹrin ọdún ó lé ogoji (840) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. Gbogbo ọdún tí Kenani gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé mẹ́wàá (910) kí ó tó kú. Nígbà tí Mahalaleli di ẹni ọdún marundinlaadọrin, ó bí Jaredi. Lẹ́yìn tí ó bí Jaredi, ó gbé ẹgbẹrin ọdún ó lé ọgbọ̀n (830) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. Gbogbo ọdún tí Mahalaleli gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó dín marun-un (895) kí ó tó kú. Nígbà tí Jaredi di ẹni ọdún mejilelọgọjọ (162) ó bí Enọku. Lẹ́yìn tí ó bí Enọku, ó gbé ẹgbẹrin (800) ọdún láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. Gbogbo ọdún tí Jaredi gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé mejilelọgọta (962) kí ó tó kú. Nígbà tí Enọku di ẹni ọdún marundinlaadọrin ó bí Metusela. Lẹ́yìn tí ó bí Metusela, ó wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun fún ọọdunrun (300) ọdún, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. Gbogbo ọdún tí Enọku gbé láyé jẹ́ ọọdunrun ọdún ó lé marundinlaadọrin (365). Enọku wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun, nígbà tí ó yá, wọn kò rí i mọ́ nítorí pé Ọlọrun mú un lọ. Nígbà tí Metusela di ẹni ọgọsan-an ọdún ó lé meje (187) ó bí Lamẹki. Lẹ́yìn tí ó bí Lamẹki, ó gbé ẹẹdẹgbẹrin ọdún ó lé mejilelọgọrin (782) sí i láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. Gbogbo ọdún tí Metusela gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé mọkandinlaadọrin (969) kí ó tó kú. Nígbà tí Lamẹki di ẹni ọdún mejilelọgọsan-an (182), ó bí ọmọkunrin kan. Ó sọ ọ́ ní Noa, ó ní: “Eléyìí ni yóo mú ìtura wá fún wa ninu iṣẹ́ ati wahala wa tí à ń ṣe lórí ilẹ̀ tí OLUWA ti fi gégùn-ún.” Lẹ́yìn tí Lamẹki bí Noa, ó gbé ọdún marundinlẹgbẹta (595) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. Gbogbo ọdún tí Lamẹki gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ọdún ó lé mẹtadinlọgọrin (777) kí ó tó kú. Nígbà tí Noa di ẹni ẹẹdẹgbẹta (500) ọdún, ó bí Ṣemu, Hamu ati Jafẹti. Nígbà tí eniyan bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ sí i lórí ilẹ̀, tí wọ́n sì ń bí ọmọbinrin, nígbà náà ni àwọn ẹ̀dá ọ̀run lọkunrin ṣe akiyesi pé àwọn ọmọbinrin tí eniyan ń bí lẹ́wà gidigidi, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ èyí tí ó wù wọ́n lára wọn. OLUWA bá wí pé, “N kò ní jẹ́ kí eniyan wà láàyè títí lae, nítorí pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n. Ọgọfa (120) ọdún ni wọn yóo máa gbé láyé.” Àwọn òmìrán wà láyé ní ayé ìgbà náà, wọ́n tilẹ̀ tún wà láyé fún àkókò kan lẹ́yìn rẹ̀. Nígbà tí àwọn ọmọkunrin Ọlọrun fẹ́ aya láàrin àwọn ọmọ eniyan, àwọn ọmọ tí wọ́n bí ni àwọn òmìrán wọnyi. Àwọn ni wọ́n jẹ́ akọni ati olókìkí nígbà náà. Nígbà tí OLUWA rí i pé ìwà burúkú eniyan ti pọ̀ jù láyé, ati pé kìkì ibi ni èrò inú wọn nígbà gbogbo, inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi pé ó dá eniyan sí ayé, ó sì dùn ún, tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi wí pé, “N óo pa àwọn ẹ̀dá alààyè tí mo dá run lórí ilẹ̀ ayé, ati eniyan ati ẹranko ati àwọn ohun tí ń fàyà fà káàkiri lórí ilẹ̀, ati ẹyẹ, gbogbo wọn ni n óo parun, nítorí ó bà mí ninu jẹ́ pé mo dá wọn.” Ṣugbọn Noa rí ojurere OLUWA. Ìtàn ìran Noa nìyí: Noa jẹ́ olódodo, òun nìkan ṣoṣo ni eniyan pípé ní àkókò tirẹ̀, ó sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu OLUWA. Ó bí ọmọkunrin mẹta tí orúkọ wọn ń jẹ́ Ṣemu, Hamu, ati Jafẹti. Ayé kún fún ìwà ìbàjẹ́ lójú Ọlọrun, ìwà jàgídíjàgan sì gba gbogbo ayé. Ọlọrun rí i pé ayé ti bàjẹ́, nítorí pé ìwà ìbàjẹ́ ni gbogbo eniyan ń hù. Ọlọrun bá sọ fún Noa pé, “Mo ti pinnu láti pa gbogbo ẹ̀dá alààyè run, nítorí ìwà ipá wọn ti gba gbogbo ayé, àtàwọn àtayé ni n óo parun. Nítorí náà, fi igi goferi kan ọkọ̀ ojú omi fún ara rẹ. Ṣe ọpọlọpọ yàrá sinu rẹ̀, kí o sì fi ọ̀dà kùn ún ninu ati lóde. Bí o óo ti kan ọkọ̀ náà nìyí: kí gígùn rẹ̀ jẹ́ ọọdunrun (300) igbọnwọ, ìbú rẹ̀ yóo jẹ́ aadọta igbọnwọ, gíga rẹ̀ yóo jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ. Kan òrùlé sí orí ọkọ̀ náà, ṣugbọn fi ààyè sílẹ̀ láàrin orí rẹ̀ ati ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ yíká, tí yóo jẹ́ ìwọ̀n igbọnwọ kan. Kí o kan ọkọ̀ náà ní ìpele mẹta, kí o sì ṣe ẹnu ọ̀nà sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. N óo jẹ́ kí ìkún omi bo gbogbo ayé, yóo pa gbogbo ẹ̀dá alààyè run, gbogbo ohun ẹlẹ́mìí tí ó wà láyé ni yóo kú. Ṣugbọn n óo bá ọ dá majẹmu, o óo wọ inú ọkọ̀ náà, ìwọ pẹlu aya rẹ ati àwọn ọmọkunrin rẹ ati àwọn aya wọn. Kí o sì mú meji meji ninu gbogbo ohun alààyè, kí wọ́n lè wà láàyè pẹlu rẹ, takọ-tabo ni kí o mú wọn. Meji meji yóo tọ̀ ọ́ wá ninu oríṣìíríṣìí àwọn ẹyẹ, ati oríṣìíríṣìí àwọn ẹran ọ̀sìn, ati oríṣìíríṣìí àwọn ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀, kí o lè mú kí wọ́n wà láàyè pẹlu rẹ. Kí o sì kó oniruuru oúnjẹ sinu ọkọ̀ náà fún ara rẹ ati fún wọn.” Noa bá ṣe gbogbo ohun tí Ọlọrun pàṣẹ fún un. Nígbà tí ó yá OLUWA sọ fún Noa pé, “Wọ inú ọkọ̀ lọ, ìwọ ati àwọn ará ilé rẹ, nítorí pé ìwọ nìkan ni o jẹ́ olódodo sí mi ní gbogbo ayé. Ninu gbogbo ẹran tí ó bá jẹ́ mímọ́, mú wọn ní takọ-tabo, meje meje, ṣugbọn ninu gbogbo ẹran tí kò bá jẹ́ mímọ́, mú akọ kan ati abo kan. Mú takọ-tabo meje meje ninu àwọn ẹyẹ, kí irú wọn lè wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé. Nítorí pé ọjọ́ meje ló kù tí n óo bẹ̀rẹ̀ sí rọ òjò sórí ilẹ̀ fún ogoji ọjọ́ tọ̀sán-tòru, gbogbo ẹ̀dá alààyè tí mo dá ni yóo sì parun lórí ilẹ̀ ayé.” Noa bá ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún un. Noa jẹ́ ẹni ẹgbẹta (600) ọdún nígbà tí ìkún omi bo ilẹ̀ ayé. Noa wọ inú ọkọ̀ lọ, òun ati aya rẹ̀ ati àwọn ọmọ rẹ̀ pẹlu aya wọn, láti sá àsálà kúrò lọ́wọ́ ìkún omi. Gbogbo ẹran ati àwọn tí wọ́n mọ́ ati àwọn tí wọn kò mọ́, àwọn ẹyẹ ati gbogbo ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀, ní meji meji, àtakọ àtabo, gbogbo wọn bá Noa wọ inú ọkọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pa á láṣẹ fún Noa. Lẹ́yìn ọjọ́ keje, ìkún omi bo ilẹ̀ ayé. Ní ọjọ́ kẹtadinlogun oṣù keji ọdún tí Noa di ẹni ẹgbẹta (600) ọdún, ni orísun alagbalúgbú omi tí ó wà ninu ọ̀gbun ńlá lábẹ́ ilẹ̀ ya, tí gbogbo fèrèsé omi tí ó wà ní ojú ọ̀run ṣí sílẹ̀, òjò sì rọ̀ fún ogoji ọjọ́, tọ̀sán-tòru. Ní ọjọ́ náà gan-an ni Noa wọ inú ọkọ̀ lọ, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ mẹtẹẹta, Ṣemu, Hamu, ati Jafẹti ati aya rẹ̀ ati àwọn aya àwọn ọmọ rẹ̀ mẹtẹẹta; pẹlu àwọn ẹranko ati àwọn ẹran ọ̀sìn, ati àwọn ohun tí ń fàyà fà káàkiri lórí ilẹ̀, ati oniruuru àwọn ẹyẹ. Gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè patapata ni wọ́n wọ inú ọkọ̀ tọ Noa lọ ní meji meji. Gbogbo àwọn ohun ẹlẹ́mìí, akọ kan, abo kan, ní oríṣìí kọ̀ọ̀kan wọlé gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pàṣẹ fún Noa. OLUWA bá ti ìlẹ̀kùn ọkọ̀ náà. Ìkún omi wà lórí ilẹ̀ fún ogoji ọjọ́. Omi náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ fi léfòó lójú omi. Bí omi náà ti ń pọ̀ sí i ni ọkọ̀ náà ń lọ síhìn-ín sọ́hùn-ún lórí rẹ̀. Omi náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi bo gbogbo àwọn òkè gíga tí wọ́n wà láyé mọ́lẹ̀. Ó sì tún pọ̀ sí i títí tí ó fi ga ju àwọn òkè gíga lọ ní igbọnwọ mẹẹdogun (mita 7). Gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé ni wọ́n kú patapata, ati ẹyẹ, ati ẹran ọ̀sìn, ati ẹranko, ati àwọn ohun tí wọn ń fàyà fà ati eniyan. Gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń mí lórí ilẹ̀ ayé patapata ni wọ́n kú. Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe pa gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà láyé run: gbogbo eniyan, gbogbo ẹranko, gbogbo ohun tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ ati ẹyẹ. Noa nìkan ni kò kú ati àwọn tí wọ́n jọ wà ninu ọkọ̀ pẹlu rẹ̀. Aadọjọ (150) ọjọ́ gbáko ni omi fi bo gbogbo ilẹ̀. Ṣugbọn Ọlọrun ranti Noa, ati gbogbo ẹranko, ati ẹran ọ̀sìn tí ó wà pẹlu rẹ̀ ninu ọkọ̀. Nítorí náà, Ọlọrun mú kí afẹ́fẹ́ kan fẹ́ sórí ilẹ̀, omi náà sì bẹ̀rẹ̀ sí fà. Ọlọrun sé orísun omi tí ó wà lábẹ́ ilẹ̀, ó ti àwọn fèrèsé ojú ọ̀run, òjò náà sì dá. Omi bá bẹ̀rẹ̀ sí fà lórí ilẹ̀. Lẹ́yìn aadọjọ (150) ọjọ́, omi náà fà tán. Ní ọjọ́ kẹtadinlogun oṣù keje, ìdí ọkọ̀ náà kanlẹ̀ lórí òkè Ararati. Omi náà sì ń fà sí i títí di oṣù kẹwaa. Ní ọjọ́ kinni oṣù náà ni ṣóńṣó orí àwọn òkè ńlá hàn síta. Lẹ́yìn ogoji ọjọ́, Noa ṣí fèrèsé ọkọ̀ tí ó kàn. Ó rán ẹyẹ ìwò kan jáde. Ẹyẹ yìí bẹ̀rẹ̀ sí fò káàkiri títí tí omi fi gbẹ lórí ilẹ̀. Ó tún rán ẹyẹ àdàbà kan jáde láti lọ wò ó bóyá omi ti gbẹ lórí ilẹ̀, ṣugbọn àdàbà náà kò rí ibi tí ó lè bà sí nítorí pé omi bo gbogbo ilẹ̀, ó bá fò pada tọ Noa lọ ninu ọkọ̀. Noa na ọwọ́ jáde láti inú ọkọ̀, ó sì mú un wọlé. Ó dúró fún ọjọ́ meje kí ó tó tún rán àdàbà náà jáde. Àdàbà náà fò pada ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà pẹlu ewé olifi tútù ní ẹnu rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Noa ṣe mọ̀ pé omi ti fà lórí ilẹ̀. Ó tún dúró fún ọjọ́ meje sí i, lẹ́yìn náà, ó tún rán àdàbà náà jáde, ṣugbọn àdàbà náà kò pada sọ́dọ̀ Noa mọ́. Ní ọjọ́ kinni oṣù kinni ọdún tí Noa di ẹni ọdún mọkanlelẹgbẹta (601), omi gbẹ tán lórí ilẹ̀. Noa ṣí òrùlé ọkọ̀, ó yọjú wo ìta, ó sì rí i pé ilẹ̀ ti gbẹ. Ní ọjọ́ kẹtadinlọgbọn oṣù keji ni ilẹ̀ gbẹ tán patapata. Ọlọrun sọ fún Noa pé, “Jáde kúrò ninu ọkọ̀, ìwọ ati aya rẹ, ati àwọn ọmọ rẹ, ati àwọn aya wọn. Kó gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹlu rẹ jáde, àwọn ẹyẹ, ẹranko ati àwọn ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀, kí wọ́n lè máa bímọ lémọ, kí wọ́n sì pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ ayé.” Noa bá jáde kúrò ninu ọkọ̀, òun ati aya rẹ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati àwọn aya wọn, pẹlu gbogbo àwọn ẹranko, gbogbo àwọn ohun tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ ati àwọn ẹyẹ. Gbogbo àwọn ohun tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ patapata ni wọ́n bá Noa jáde kúrò ninu ọkọ̀. Noa tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA, ó mú ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ẹran ati àwọn ẹyẹ tí wọ́n mọ́, ó fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ náà. Nígbà tí OLUWA gbọ́ òórùn dídùn ẹbọ náà, ó wí ninu ara rẹ̀ pé, “N kò ní fi ilẹ̀ gégùn-ún mọ́ nítorí eniyan, nítorí pé, láti ìgbà èwe wọn wá ni èrò inú wọn ti jẹ́ kìkì ibi. Bẹ́ẹ̀ ni n kò ní pa gbogbo ẹ̀dá alààyè run mọ́ bí mo ti ṣe yìí. Níwọ̀n ìgbà tí ayé bá ṣì wà, ìgbà gbígbìn ati ìgbà ìkórè kò ní ṣàìwà, bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbà òtútù ati ìgbà ooru, ìgbà òjò ati ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn yóo sì máa wà pẹlu.” Ọlọrun súre fún Noa ati àwọn ọmọ rẹ̀, ó ní, “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ máa pọ̀ sí i, kí ẹ sì kún gbogbo ayé. Gbogbo ẹranko tí ó wà láyé, gbogbo ẹyẹ, gbogbo ẹja tí ń bẹ ninu omi, ati gbogbo ohun tí ń rìn káàkiri ni yóo máa bẹ̀rù yín, ìkáwọ́ yín ni mo fi gbogbo wọn sí. Gbogbo ohun alààyè tí ń rìn ni yóo jẹ́ oúnjẹ fún yín, bí mo ti fún yín ní gbogbo ewéko, bẹ́ẹ̀ náà ni mo fún yín ní ohun gbogbo. Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran ti òun ti ẹ̀jẹ̀, nítorí pé, ninu ẹ̀jẹ̀ ni ìyè wà. Dájúdájú n óo gbẹ̀san lára ẹnikẹ́ni tí ó bá paniyan, kì báà jẹ́ ẹranko ni ó paniyan tabi eniyan ni ó pa ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, pípa ni a óo pa olúwarẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá paniyan, pípa ni a óo pa òun náà, nítorí pé ní àwòrán Ọlọrun fúnrarẹ̀ ni ó dá eniyan. “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ máa pọ̀ sí i, kí ẹ sì kún gbogbo ayé.” Lẹ́yìn náà Ọlọrun sọ fún Noa ati àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Wò ó! Mo bá ẹ̀yin ati atọmọdọmọ yín dá majẹmu, ati gbogbo ẹ̀dá alààyè tí wọ́n wà pẹlu yín: Gbogbo àwọn ẹyẹ, àwọn ẹran ọ̀sìn ati àwọn ẹranko tí wọ́n bá yín jáde ninu ọkọ̀, majẹmu náà ni pé, lae, n kò tún ní fi ìkún omi pa gbogbo ẹ̀dá alààyè run mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí ìkún omi tí yóo pa ayé rẹ́ mọ́. Ohun tí yóo jẹ́ àmì majẹmu tí mo ń bá ẹ̀yin ati gbogbo ẹ̀dá alààyè dá, tí yóo sì wà fún atọmọdọmọ yín ní ọjọ́ iwájú nìyí: mo fi òṣùmàrè mi sí ojú ọ̀run, òun ni yóo máa jẹ́ àmì majẹmu tí mo bá ayé dá. Nígbàkúùgbà tí mo bá mú kí òjò ṣú ní ojú ọ̀run, tí òṣùmàrè bá sì yọ jáde, n óo ranti majẹmu tí mo bá ẹ̀yin ati gbogbo ẹ̀dá alààyè dá pé, omi kò ní kún débi pé yóo pa ayé rẹ́ mọ́. Nígbà tí òṣùmàrè bá yọ, n óo wò ó, n óo sì ranti majẹmu ayérayé tí èmi Ọlọrun bá gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà láyé dá. Èyí ni majẹmu tí mo bá gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà láyé dá.” Àwọn ọmọ Noa tí wọ́n jáde ninu ọkọ̀ ni: Ṣemu, Hamu ati Jafẹti. Hamu ni ó bí Kenaani. Àwọn ọmọ Noa mẹtẹẹta yìí ni baba ńlá gbogbo ayé. Noa ni ẹni kinni tí ó kọ́kọ́ ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀, tí ó gbin ọgbà àjàrà. Noa mu àmupara ninu ọtí waini ọgbà rẹ̀, ó sì sùn sinu àgọ́ rẹ̀ ní ìhòòhò. Hamu, baba Kenaani, rí baba rẹ̀ ní ìhòòhò, ó lọ sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀ mejeeji lóde. Ṣemu ati Jafẹti bá mú aṣọ kan, wọ́n fà á kọ́ èjìká wọn, wọ́n fi ẹ̀yìn rìn lọ sí ibi tí baba wọn sùn sí, wọ́n sì dà á bò ó, wọ́n kọ ojú sí ẹ̀gbẹ́ kan, wọn kò sì rí ìhòòhò baba wọn. Nígbà tí ọtí dá lójú Noa, tí ó gbọ́ ohun tí àbíkẹ́yìn rẹ̀ ṣe sí i, Ó ní, “Ẹni ègún ni Kenaani, ẹrú lásánlàsàn ni yóo jẹ́ fún àwọn arakunrin rẹ̀.” Ó tún fi kún un pé, “Kí OLUWA Ọlọrun mi bukun Ṣemu, ẹrú rẹ̀ ni Kenaani yóo máa ṣe. Kí Ọlọrun sọ ìdílé Jafẹti di pupọ, kí ó máa gbé ninu àgọ́ Ṣemu, ẹrú rẹ̀ ni Kenaani yóo máa ṣe.” Ọọdunrun ọdún ó lé aadọta (350) ni Noa tún gbé sí i lẹ́yìn ìkún omi. Noa kú nígbà tí ó di ẹni ẹgbẹrun ọdún ó dín aadọta (950). Ìran Noa nìyí: àwọn ọmọ rẹ̀ ni Ṣemu, Hamu ati Jafẹti. Lẹ́yìn ìkún omi, àwọn mẹtẹẹta bí ọmọ tiwọn. Àwọn ọmọ Jafẹti ni: Gomeri, Magogu, Madai, Jafani, Tubali, Meṣeki ati Tirasi. Àwọn ọmọ Gomeri ni: Aṣikenasi, Rifati, ati Togama. Àwọn ọmọ Jafani ni: Eliṣai, Taṣiṣi, Kitimu ati Dodanimu. Àwọn ni baba ńlá àwọn tí wọn ń gbé etí òkun ati àwọn erékùṣù, tí wọ́n tàn káàkiri. Àwọn ọmọ Jafẹti nìwọ̀nyí ní ìdílé ìdílé wọn, olukuluku ní agbègbè tirẹ̀. Oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè ni wọ́n, wọ́n sì ń sọ oríṣìíríṣìí èdè. Àwọn ọmọ Hamu ni: Kuṣi, Ijipti, Puti ati Kenaani. Àwọn ọmọ Kuṣi ni: Seba, Hafila, Sabita, Raama ati Sabiteka. Àwọn ọmọ Raama ni: Ṣeba ati Dedani. Kuṣi ni baba Nimrodu, Nimrodu yìí ni ẹni kinni tí wọ́n mọ̀ ní akọni láyé. Pẹlu àtìlẹ́yìn OLUWA, Nimrodu di ògbójú ọdẹ, tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n máa ń fi orúkọ rẹ̀ súre fún eniyan pé, “Kí OLUWA sọ ọ́ di ògbójú ọdẹ bíi Nimrodu.” Ìjọba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti Babeli, Ereki ati Akadi. Àwọn ìlú mẹtẹẹta yìí wà ní ilẹ̀ Babiloni. Láti ibẹ̀ ni ó ti lọ sí Asiria, ó sì tẹ Ninefe dó, ati Rehoboti Iri, ati Kala, ati ìlú ńlá tí wọn ń pè ní Reseni tí ó wà láàrin Ninefe ati Kala. Ijipti ni ó bí Ludimu, Anamimu, Lehabimu, Nafutuhimu, Patirusimu, Kasiluhimu, (lọ́dọ̀ ẹni tí àwọn ará Filistia ti ṣẹ̀) ati Kafitorimu. Àkọ́bí Kenaani ni Sidoni, òun náà ni ó bí Heti. Kenaani yìí kan náà ni baba ńlá àwọn ará Jebusi, àwọn ará Amori, àwọn ará Girigaṣi, àwọn ará Hifi, àwọn ará Ariki, àwọn ará Sini, àwọn ará Arifadi, àwọn ará Semari, ati àwọn ará Hamati. Lẹ́yìn náà ni ìran àwọn ará Kenaani tàn káàkiri. Ilẹ̀ àwọn ará Kenaani bẹ̀rẹ̀ láti Sidoni, ní ìhà Gerari, ó lọ títí dé Gasa, ati sí ìhà Sodomu, Gomora, Adima, ati Seboimu títí dé Laṣa. Àwọn ọmọ Hamu nìwọ̀nyí ní ìdílé ìdílé wọn, olukuluku ní agbègbè tirẹ̀, oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè ni wọ́n, wọ́n sì ń sọ oríṣìíríṣìí èdè. Ṣemu, ẹ̀gbọ́n Jafẹti, náà bí àwọn ọmọ tirẹ̀, òun ni baba ńlá gbogbo àwọn ọmọ Eberi. Òun náà ni ó bí Elamu, Aṣuri, Apakiṣadi, Ludi, ati Aramu. Àwọn ọmọ Aramu ni: Usi, Huli, Geteri, ati Maṣi. Apakiṣadi ni baba Ṣela, Ṣela sì ni baba Eberi. Àwọn ọmọkunrin meji ni Eberi bí, orúkọ ekinni ni Pelegi, nítorí pé ní ìgbà tirẹ̀ ni ayé pínyà, orúkọ ekeji ni Jokitani. Jokitani ni baba Alimodadi, Ṣelefu, Hasamafeti, Jera, Hadoramu, Usali, Dikila, Obali, Abimaeli, Ṣeba, Ofiri, Hafila, ati Jobabu, àwọn ni ọmọ Jokitani. Ilẹ̀ tí wọn ń gbé bẹ̀rẹ̀ láti Meṣa, ní ìhà Sefari títí dé ilẹ̀ olókè ti ìhà ìlà oòrùn. Àwọn ni ọmọ Ṣemu, ní ìdílé ìdílé wọn, olukuluku ní agbègbè tirẹ̀. Oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè ni wọ́n, wọ́n sì ń sọ oríṣìíríṣìí èdè. Ìdílé àwọn ọmọ Noa ni wọ́n jẹ́, gẹ́gẹ́ bí ìran wọn ní orílẹ̀-èdè wọn. Lára wọn ni àwọn orílẹ̀-èdè ti tàn ká gbogbo ayé lẹ́yìn ìkún omi. Nígbà kan èdè kan ṣoṣo ni ó wà láyé, ọ̀rọ̀ bíi mélòó kan ni gbogbo wọ́n sì ń lò. Bí àwọn eniyan ṣe ń ṣí káàkiri ní ìhà ìlà oòrùn, wọ́n rí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú ní agbègbè Babiloni, wọ́n sì tẹ̀dó sibẹ. Wọ́n sọ fún ara wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á ṣe bíríkì, kí á sì sun wọ́n jiná dáradára.” Bíríkì ni wọ́n lò dípò òkúta, wọ́n sì lo ọ̀dà ilẹ̀ dípò ọ̀rọ̀. Wọ́n sọ fún ara wọn pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á kọ́ ìlú ńlá kan, kí á sì kọ́ ilé ìṣọ́ gíga kan tí orí rẹ̀ yóo kan ojú ọ̀run gbọ̀ngbọ̀n, kí á baà lè di olókìkí, kí á má baà fọ́n káàkiri orí ilẹ̀ ayé.” OLUWA sọ̀kalẹ̀ láti wo ìlú tí àwọn ọmọ eniyan ń tẹ̀dó ati ilé ìṣọ́ gíga tí wọn ń kọ́. OLUWA wí pé, “Ọ̀kan ni gbogbo àwọn eniyan wọnyi, èdè kan ṣoṣo ni wọ́n sì ń sọ, wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ àwọn ohun tí wọn yóo ṣe ni, kò sì ní sí ohun kan tí wọn bá dáwọ́lé láti ṣe tí yóo dẹtì fún wọn. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á sọ̀kalẹ̀ lọ bá wọn, kí á dà wọ́n ní èdè rú, kí wọn má baà gbọ́ èdè ara wọn mọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe fọ́n wọn káàkiri sí gbogbo orílẹ̀ ayé, wọ́n pa ìlú náà tí wọn ń tẹ̀dó tì. Ìdí nìyí tí wọ́n ṣe pe orúkọ ìlú náà ní Babeli, nítorí níbẹ̀ ni OLUWA ti da èdè gbogbo ayé rú, láti ibẹ̀ ni ó sì ti fọ́n wọn káàkiri gbogbo orílẹ̀ ayé. Àkọsílẹ̀ ìran Ṣemu nìyí: ọdún keji lẹ́yìn tí ìkún omi ṣẹlẹ̀, tí Ṣemu di ẹni ọgọrun-un (100) ọdún ni ó bí Apakiṣadi. Lẹ́yìn tí Ṣemu bí Apakiṣadi tán, ó tún gbé ẹẹdẹgbẹta (500) ọdún sí i láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. Nígbà tí Apakiṣadi di ẹni ọdún marundinlogoji ni ó bí Ṣela. Ó tún gbé ọdún mẹtalenirinwo (403) sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Ṣela, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. Nígbà tí Ṣela di ẹni ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Eberi. Ó tún gbé ọdún mẹtalenirinwo (403) sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Eberi tán, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. Nígbà tí Eberi di ẹni ọdún mẹrinlelọgbọn ni ó bí Pelegi. Eberi tún gbé ojilenirinwo ó dín mẹ́wàá (430) ọdún sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Pelegi tán, ó tún bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. Nígbà tí Pelegi di ẹni ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Reu. Ó tún gbé igba ọdún ó lé mẹsan-an (209) sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Reu, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. Nígbà tí Reu di ẹni ọdún mejilelọgbọn ni ó bí Serugi. Ó tún gbé igba ọdún ó lé meje (207) sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Serugi, ó sì tún bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. Nígbà tí Serugi di ẹni ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Nahori. Ó tún gbé igba (200) ọdún sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Nahori, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. Nígbà tí Nahori di ẹni ọdún mọkandinlọgbọn ni ó bí Tẹra. Ó tún gbé igba ọdún ó lé mọkandinlogun (219) sí i láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. Nígbà tí Tẹra di ẹni aadọrin ọdún ni ó bí Abramu, Nahori, ati Harani. Àkọsílẹ̀ ìran Tẹra nìyí: Tẹra ni baba Abramu, Nahori ati Harani. Harani sì ni baba Lọti. Harani kú ṣáájú Tẹra, baba rẹ̀, Uri ìlú rẹ̀, tí ó wà ní ilẹ̀ Kalidea ni ó kú sí. Abramu ati Nahori ní iyawo, Sarai ni orúkọ iyawo Abramu, orúkọ iyawo ti Nahori sì ni Milika, ọmọbinrin Harani. Harani ni baba Milika ati Isika. Àgàn ni Sarai, kò bímọ. Tẹra mú Abramu ọmọ rẹ̀, ati Lọti, ọmọ Harani tíí ṣe ọmọ Tẹra, ati Sarai aya Abramu, ó kó gbogbo wọn jáde kúrò ní Uri ti ilẹ̀ Kalidea, wọ́n ń lọ sí ilẹ̀ Kenaani. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé Harani, wọ́n tẹ̀dó sibẹ. Nígbà tí Tẹra di ẹni igba ọdún ó lé marun-un (205), ó kú ní ilẹ̀ Harani. Ní ọjọ́ kan, Ọlọrun sọ fún Abramu pé, “Jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ, láàrin àwọn ìbátan rẹ, ati kúrò ní ilé baba rẹ lọ sí ilẹ̀ kan tí n óo fi hàn ọ́. N óo sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, n óo bukun ọ, n óo sì sọ orúkọ rẹ di ńlá, tóbẹ́ẹ̀ tí o óo jẹ́ ibukun fún àwọn eniyan. N óo súre fún àwọn tí wọ́n bá súre fún ọ, bí ẹnikẹ́ni bá sì fi ọ́ bú, n óo fi òun náà bú. Nípasẹ̀ rẹ ni n óo bukun gbogbo ìdílé ayé.” Bẹ́ẹ̀ ni Abramu ṣe jáde lọ, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ fún un, Lọti sì bá a lọ. Abramu jẹ́ ẹni ọdún marundinlọgọrin nígbà tí ó jáde kúrò ní Harani. Abramu mú Sarai iyawo rẹ̀, ati Lọti, ọmọ arakunrin rẹ̀ lọ́wọ́ lọ, ati gbogbo ohun ìní wọn ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n jẹ́ tiwọn ní Harani. Wọ́n jáde, wọ́n gbọ̀nà ilẹ̀ Kenaani. Nígbà tí wọ́n dé ilẹ̀ Kenaani, Abramu la ilẹ̀ náà kọjá lọ sí ibi igi Oaku ti More, ní Ṣekemu. Àwọn ará Kenaani ni wọ́n ń gbé ilẹ̀ náà nígbà náà. Nígbà náà ni OLUWA fara han Abramu, ó wí pé, “Àwọn ọmọ ati ọmọ ọmọ rẹ ni n óo fi ilẹ̀ yìí fún.” Abramu bá tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún OLUWA tí ó fara hàn án. Lẹ́yìn náà Abramu kúrò níbẹ̀, ó lọ sí orí òkè tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn Bẹtẹli, ó pàgọ́ sibẹ. Bẹtẹli wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn ibùdó rẹ̀, Ai sì wà ní ìhà ìlà oòrùn. Ó tún tẹ́ pẹpẹ mìíràn níbẹ̀, ó sì sin OLUWA. Abramu ṣá ń lọ sí ìhà gúsù ní agbègbè tí à ń pè ní Nẹgẹbu. Ní àkókò kan, ìyàn mú gidigidi ní ilẹ̀ Kenaani. Ìyàn náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí Abramu níláti kó lọ sí Ijipti, láti máa gbé ibẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. Nígbà tí ó ń wo Ijipti lókèèrè, ó sọ fún Sarai aya rẹ̀ pé, “Ṣé ìwọ náà mọ̀ pé arẹwà obinrin ni ọ́, ati pé bí àwọn ará Ijipti bá ti fi ojú kàn ọ́, wọn yóo wí pé, ‘Iyawo rẹ̀ nìyí’, wọn yóo pa mí, wọn yóo sì dá ọ sí. Wò ó, wí fún wọn pé tẹ̀gbọ́n-tàbúrò ni wá, kí wọ́n lè ṣe mí dáradára, kí wọ́n má baà tìtorí rẹ pa mí.” Nígbà tí Abramu wọ Ijipti, àwọn ará Ijipti rí i pé arẹwà obinrin ni aya rẹ̀. Nígbà tí àwọn ìjòyè ọba Farao rí i, wọ́n pọ́n ọn lójú Farao, wọ́n sì mú un wá sí ààfin rẹ̀. Nítorí ti Sarai, Farao ṣe Abramu dáradára. Abramu di ẹni tí ó ní ọpọlọpọ aguntan, akọ mààlúù, akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, iranṣẹkunrin, iranṣẹbinrin, abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ati ràkúnmí. Ṣugbọn OLUWA fi àrùn burúkú bá Farao ati gbogbo ìdílé rẹ̀ jà nítorí Sarai, aya Abramu. Farao bá pe Abramu, ó bi í pé, “Èéṣe tí o fi ṣe báyìí sí mi? Èéṣe tí o kò fi sọ fún mi pé iyawo rẹ ni Sarai? Èéṣe tí o fi sọ pé tẹ̀gbọ́n-tàbúrò ni yín, tí o jẹ́ kí n fi ṣe aya? Iyawo rẹ nìyí, gba nǹkan rẹ, kí o sì máa lọ.” Farao bá pàṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ nípa Abramu, wọ́n sì rí i pé Abramu jáde kúrò nílùú, ati òun ati aya rẹ̀, ati ohun gbogbo tí ó ní. Bẹ́ẹ̀ ni Abramu ṣe jáde kúrò ní Ijipti, ó pada lọ sí Nẹgẹbu pẹlu aya rẹ̀, ati Lọti ati ohun gbogbo tí ó ní. Abramu ní dúkìá pupọ ní àkókò yìí, ó ní ẹran ọ̀sìn, fadaka ati wúrà lọpọlọpọ. Nígbà tí ó yá, ó kúrò ní Nẹgẹbu, ó ń lọ sí Bẹtẹli, ó dé ibi tí ó kọ́kọ́ pàgọ́ sí láàrin Bẹtẹli ati Ai, níbi pẹpẹ tí ó kọ́kọ́ pa, ibẹ̀ ni ó sì ti sin OLUWA. Lọti tí ó bá Abramu lọ náà ní ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn ati agbo mààlúù ati ọpọlọpọ àgọ́ fún ìdílé rẹ̀ ati àwọn iranṣẹ rẹ̀. Ẹran ọ̀sìn àwọn mejeeji pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ náà kò fi láàyè tó mọ́ fún wọn láti jọ máa gbé pọ̀. Ìjà sì ń ṣẹlẹ̀ láàrin àwọn darandaran Abramu ati àwọn ti Lọti. Ní àkókò náà, àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Perisi ń gbé ilẹ̀ náà. Abramu bá sọ fún Lọti pé, “Má jẹ́ kí ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàrin èmi pẹlu rẹ, tabi láàrin àwọn darandaran mi ati àwọn tìrẹ. Ṣebí ara kan náà ni wá? Ilẹ̀ ló lọ jaburata níwájú rẹ yìí, jọ̀wọ́, jẹ́ kí á takété sí ara wa. Bí o bá lọ sí apá òsì, èmi á lọ sí apá ọ̀tún, bí o bá sì lọ sí apá ọ̀tún, èmi á lọ sí apá òsì.” Lọti bá gbójú sókè, ó wo gbogbo agbègbè odò Jọdani títí dé Soari, ó rí i pé gbogbo koríko ibẹ̀ ni wọ́n tutù dáradára tí ó dàbí ọgbà OLUWA ati bí ilẹ̀ Ijipti. Ní àkókò náà, OLUWA kò tíì pa ìlú Sodomu ati Gomora run. Lọti bá yan gbogbo agbègbè odò Jọdani fún ara rẹ̀, ó sì lọ sí ìhà ìlà oòrùn. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe takété sí ara wọn. Abramu ń gbé ilẹ̀ Kenaani, Lọti sì ń gbé ààrin àwọn ìlú tí ó wà ní agbègbè odò Jọdani, ó pàgọ́ rẹ̀ títí dé Sodomu. Àwọn ará Sodomu yìí jẹ́ eniyan burúkú, wọn ń dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA lọpọlọpọ. Lẹ́yìn tí Lọti ti kúrò lọ́dọ̀ Abramu, OLUWA sọ fún Abramu pé, “Gbé ojú rẹ sókè, kí o wò ó láti ibi tí o wà yìí, títí lọ sí ìhà àríwá ati sí ìhà gúsù, tún wò ó lọ sí ìhà ìlà oòrùn títí dé ìhà ìwọ̀ oòrùn. Gbogbo ilẹ̀ tí ò ń wò yìí, ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ni n óo fún títí lae. N óo mú kí àwọn ọmọ rẹ pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, tí yóo fi jẹ́ pé, àfi ẹni tí ó bá lè ka iye erùpẹ̀ ilẹ̀ ni yóo lè kà wọ́n. Dìde, kí o rìn jákèjádò ilẹ̀ náà, nítorí pé ìwọ ni n óo fún.” Nítorí náà, Abramu kó àgọ́ rẹ̀ wá sí ibi igi Oaku ti Mamure, tí ó wà ní Heburoni, níbẹ̀ ni ó ti tẹ́ pẹpẹ fún OLUWA. Nígbà kan, àwọn ọba mẹrin kan: Amrafeli, ọba Babiloni, Arioku, ọba Elasari, Kedorilaomeri, ọba Elamu, ati Tidali, ọba Goiimu, gbógun ti Bera, ọba Sodomu, Birisa ọba Gomora, Ṣinabu, ọba Adima, Ṣemeberi, ọba Seboimu ati ọba ìlú Bela (tí ó tún ń jẹ́, Soari). Gbogbo wọn pa àwọn ọmọ ogun wọn pọ̀ ní àfonífojì Sidimu (tí ó tún ń jẹ́ òkun iyọ̀). Fún ọdún mejila gbáko ni àwọn ọba maraarun yìí fi sin Kedorilaomeri, ṣugbọn ní ọdún kẹtala, wọ́n dìtẹ̀. Ní ọdún kẹrinla, Kedorilaomeri ati àwọn ọba tí wọ́n wà lẹ́yìn rẹ̀ wá, wọ́n ṣẹgun Refaimu tí ó wà ní Aṣiterotu Kanaimu. Bákan náà, wọ́n ṣẹgun àwọn Susimu tí wọ́n wà ní Hamu, àwọn Emimu tí wọ́n wà ní Ṣafe-kiriataimu, ati àwọn ará Hori ní orí Òkè Seiri, títí dé Eliparani, lẹ́bàá aṣálẹ̀. Nígbà náà ni wọ́n tó yipada tí wọ́n sì wá sí Enmiṣipati (tí ó tún ń jẹ́ Kadeṣi), wọ́n sì ṣẹgun gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Amaleki ati ti àwọn ará Amori tí ń gbé Hasasoni Tamari. Nígbà náà ni ọba Sodomu, ati ọba Gomora jáde lọ, pẹlu ọba Adima, ọba Seboimu, ati ọba Bela, (tí ó tún ń jẹ́, Soari). Wọ́n pa ogun wọn pọ̀ ní àfonífojì Sidimu. Wọ́n gbógun ti Kedorilaomeri, ọba Elamu, Tidali, ọba Goiimu, Amrafeli, ọba Babiloni ati Arioku, ọba Elasari. Ọba mẹrin dojú kọ ọba marun-un. Àfonífojì Sidimu kún fún ihò tí wọ́n ti wa ọ̀dà ilẹ̀. Bí àwọn ọmọ ogun ọba Sodomu ati àwọn ọmọ ogun ọba Gomora ti ń sálọ, àwọn kan ninu wọn jìn sinu àwọn ihò náà, àwọn yòókù sá gun orí òkè lọ. Àwọn ọ̀tá kó gbogbo ẹrù ati oúnjẹ àwọn ará Sodomu ati Gomora, wọ́n bá tiwọn lọ. Ọwọ́ wọn tẹ Lọti, ọmọ arakunrin Abramu tí ń gbé ní Sodomu, wọ́n mú un lẹ́rú, wọ́n sì kó gbogbo ẹran ọ̀sìn ati gbogbo ohun ìní rẹ̀ lọ. Nígbà náà ni ẹnìkan tí ó sá àsálà lójú ogun náà wá ròyìn fún Abramu, tí ó jẹ́ Heberu, tí ń gbé lẹ́bàá igi Oaku, ní igbó Mamure, ará Amori. Mamure ati àwọn arakunrin rẹ̀ Eṣikolu ati Aneri bá Abramu dá majẹmu. Nígbà tí Abramu gbọ́ pé wọ́n ti mú ìbátan òun lẹ́rú, ó kó ọọdunrun ó lé mejidinlogun (318) ninu àwọn ọkunrin tí wọ́n bí sinu ilé rẹ̀, tí ó sì ti kọ́ ní ogun jíjà, ó lépa àwọn tí wọ́n mú Lọti lẹ́rú lọ títí dé ilẹ̀ Dani. Ó pín àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí ní òru ọjọ́ náà. Òun ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ yí àwọn ọ̀tá náà po, wọ́n ṣí wọn nídìí, wọ́n sì lépa wọn títí dé ìlú Hoba ní apá ìhà àríwá Damasku. Abramu gba gbogbo ìkógun tí wọ́n kó pada, ó gba Lọti, ìbátan rẹ̀ pẹlu ati gbogbo ohun ìní rẹ̀, ati àwọn obinrin ati ọ̀pọ̀ àwọn eniyan mìíràn. Nígbà tí Abramu ń pada bọ̀, lẹ́yìn tí ó ti ṣẹgun Kedorilaomeri ati àwọn ọba tí wọ́n jọ pa ìmọ̀ pọ̀, ọba Sodomu jáde lọ pàdé rẹ̀ ní àfonífojì Ṣafe (tí ó tún ń jẹ́, àfonífojì ọba). Mẹlikisẹdẹki ọba Salẹmu náà mú oúnjẹ ati ọtí waini wá pàdé rẹ̀. Mẹlikisẹdẹki jẹ́ alufaa Ọlọrun Ọ̀gá Ògo. Ó súre fún Abramu, ó ní: “Kí Ọlọrun Ọ̀gá Ògo, tí ó dá ọ̀run ati ayé bukun Abramu. Ìyìn sì ni fún Ọlọrun Ọ̀gá Ògo, ẹni tí ó bá ọ ṣẹgun àwọn ọ̀tá rẹ.” Abramu bá fún Mẹlikisẹdẹki ní ìdámẹ́wàá gbogbo ìkógun tí ó kó bọ̀. Ọba Sodomu sọ fún Abramu pé, “Jọ̀wọ́, máa kó gbogbo ìkógun lọ, ṣugbọn dá àwọn eniyan mi pada fún mi.” Ṣugbọn Abramu dá a lóhùn ó ní: “Mo ti búra fún OLUWA Ọlọrun Ọ̀gá Ògo, ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé, pé, abẹ́rẹ́ lásán, n kò ní fọwọ́ mi kàn ninu ohun tí ó jẹ́ tìrẹ, kí o má baà sọ pé ìwọ ni o sọ mí di ọlọ́rọ̀. N kò ní fọwọ́ mi kan ohunkohun àfi ohun tí àwọn ọmọkunrin tí wọ́n bá mi lọ ti jẹ, ati ìpín tiwọn tí ó kàn wọ́n, ṣugbọn jẹ́ kí Aneri, Eṣikolu ati Mamure kó ìpín tiwọn.” Lẹ́yìn nǹkan wọnyi, OLUWA bá Abramu sọ̀rọ̀ lójú ìran, ó ní, “Má bẹ̀rù Abramu, n óo dáàbò bò ọ́, èrè rẹ yóo sì pọ̀ pupọ.” Ṣugbọn Abramu dáhùn pé, “OLUWA Ọlọrun, kí ni o óo fún mi, n kò tíì bímọ títí di ìsinsìnyìí! Ṣé Elieseri ará Damasku yìí ni yóo jẹ́ àrólé mi ni? O kò fún mi lọ́mọ, ẹrú tí wọ́n bí ninu ilé mi ni yóo di àrólé mi!” OLUWA bá dá a lóhùn pé, “Kì í ṣe ọkunrin yìí ni yóo jẹ́ àrólé rẹ, ọmọ bíbí inú rẹ ni yóo jẹ́ àrólé rẹ.” OLUWA bá mú un jáde, ó sì sọ fún un pé, “Wo ojú ọ̀run, kí o ka gbogbo ìràwọ̀ tí ó wà níbẹ̀ bí o bá lè kà wọ́n.” OLUWA bá sọ fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ rẹ yóo ṣe pọ̀ tó.” Abramu gba OLUWA gbọ́, OLUWA sì kà á sí olódodo. Ó sọ fún un pé “Èmi ni OLUWA tí ó mú ọ jáde láti ìlú Uri, ní ilẹ̀ Kalidea, láti fi ilẹ̀ yìí fún ọ ní ohun ìní.” Ṣugbọn Abramu bèèrè pé, “OLUWA Ọlọrun, báwo ni n óo ṣe mọ̀ pé ilẹ̀ náà yóo jẹ́ tèmi?” OLUWA dá a lóhùn, ó ní, “Mú ẹgbọ̀rọ̀ abo mààlúù ọlọ́dún mẹta kan, ati ewúrẹ́ ọlọ́dún mẹta kan, ati àgbò ọlọ́dún mẹta kan, ati àdàbà kan ati ọmọ ẹyẹlé kan wá.” Ó kó gbogbo wọn wá fún OLUWA, ó là wọ́n sí meji meji, ó sì tẹ́ wọn sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn lọ, ṣugbọn kò la àdàbà ati ẹyẹlé náà. Nígbà tí àwọn ẹyẹ tí wọ́n máa ń jẹ òkú ẹran rábàbà wá sí ibi tí Abramu to àwọn ẹran náà sí, ó lé wọn. Nígbà tí oòrùn ń wọ̀ lọ, oorun bẹ̀rẹ̀ sí kun Abramu, ó sì sun àsùnwọra, jìnnìjìnnì mú un, òkùnkùn biribiri sì bò ó mọ́lẹ̀. Nígbà náà ni OLUWA sọ fún un pé, “Mọ̀ dájúdájú pé àwọn ọmọ rẹ yóo lọ gbé ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiwọn, wọn yóo di ẹrú níbẹ̀, àwọn ará ibẹ̀ yóo sì mú wọn sìn fún irinwo (400) ọdún. Ṣugbọn n óo mú ìdájọ́ wá sórí orílẹ̀-èdè náà tí wọn yóo sìn. Àṣẹ̀yìnwá, àṣẹ̀yìnbọ̀, wọn yóo jáde kúrò níbẹ̀ pẹlu ọpọlọpọ dúkìá. Ìwọ náà yóo dàgbà, o óo di arúgbó, ní ọjọ́ àtisùn rẹ, ikú wọ́ọ́rọ́wọ́ ni o óo kú. Atọmọdọmọ rẹ kẹrin ni yóo pada wá síhìn-ín, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará Amori kò tíì kún ojú òṣùnwọ̀n.” Nígbà tí oòrùn wọ̀, tí ilẹ̀ sì ṣú, kòkò iná tí ó ń rú èéfín ati ìtùfù tí ń jò lálá kan kọjá láàrin àwọn ẹran tí Abramu tò sílẹ̀. Ní ọjọ́ náà ni OLUWA bá a dá majẹmu, ó sọ pé, “Àwọn ọmọ rẹ ni n óo fi ilẹ̀ yìí fún, láti odò Ijipti títí dé odò ńlá nì, àní odò Yufurate, ilẹ̀ àwọn ará Keni, ti àwọn ará Kenisi, ti àwọn ará Kadimoni, ti àwọn ará Hiti, ti àwọn ará Perisi, ti àwọn ará Refaimu, ti àwọn ará Amori, ti àwọn ará Kenaani, ti àwọn ará Girigaṣi ati ti àwọn ará Jebusi.” Sarai, aya Abramu, kò bímọ fún un. Ṣugbọn ó ní ẹrubinrin ará Ijipti kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hagari. Ní ọjọ́ kan, Sarai pe Abramu, ó sọ fún un pé, “Ṣé o rí i pé OLUWA kò jẹ́ kí n bímọ, nítorí náà bá ẹrubinrin mi yìí lòpọ̀, ó le jẹ́ pé láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni n óo ti ní ọmọ.” Abramu sì gba ọ̀rọ̀ Sarai aya rẹ̀. Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tí Abramu ti dé ilẹ̀ Kenaani ni Sarai, aya rẹ̀ fa Hagari, ará Ijipti, ẹrubinrin rẹ̀ fún un, láti fi ṣe aya. Abramu bá Hagari lòpọ̀, Hagari sì lóyún. Nígbà tí ó rí i pé òun lóyún, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi ojú tẹmbẹlu Sarai, oluwa rẹ̀. Sarai bá sọ fún Abramu pé, “Ibi tí Hagari ń ṣe sí mi yìí yóo dà lé ọ lórí. Èmi ni mo fa ẹrubinrin mi lé ọ lọ́wọ́, nígbà tí ó rí i pé òun lóyún tán, mo wá di ẹni yẹ̀yẹ́ lójú rẹ̀. OLUWA ni yóo ṣe ìdájọ́ láàrin èmi pẹlu rẹ.” Ṣugbọn Abramu dá a lóhùn pé, “Ṣebí ìkáwọ́ rẹ ni ẹrubinrin rẹ wà, ṣe é bí ó bá ti wù ọ́.” Sarai bá bẹ̀rẹ̀ sí fòòró ẹ̀mí Hagari, Hagari sì sá kúrò nílé. Angẹli OLUWA rí i lẹ́bàá orísun omi kan tí ó wà láàrin aṣálẹ̀ lọ́nà Ṣuri. Ó pè é, ó ní, “Hagari, ẹrubinrin Sarai, níbo ni o ti ń bọ̀, níbo ni o sì ń lọ?” Hagari dáhùn pé, “Mò ń sálọ fún Sarai, oluwa mi ni.” Angẹli OLUWA náà wí fún un pé, “Pada tọ oluwa rẹ lọ, kí o sì tẹríba fún un.” Angẹli OLUWA náà tún wí fún un pé, “N óo sọ atọmọdọmọ rẹ di pupọ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kì yóo le kà wọ́n tán. Wò ó! oyún tí ó wà ninu rẹ, ọkunrin ni o óo fi bí, o óo sọ ọmọ náà ní Iṣimaeli, nítorí OLUWA ti rí gbogbo ìyà tí ń jẹ ọ́. Oníjàgídíjàgan ẹ̀dá ni yóo jẹ́, bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ inú igbó, yóo máa bá gbogbo eniyan jà, gbogbo eniyan yóo sì máa bá a jà, títa ni yóo sì takété sí àwọn ìbátan rẹ̀.” Nítorí náà, ó pe orúkọ OLUWA tí ó bá a sọ̀rọ̀ ní “Ìwọ ni Ọlọrun tí ń rí nǹkan.” Nítorí ó wí pé, “Ṣé nítòótọ́ ni mo rí Ọlọrun, tí mo sì tún wà láàyè?” Nítorí náà ni wọ́n ṣe ń pe orúkọ kànga náà ní Beeri-lahai-roi, ó wà láàrin Kadeṣi ati Beredi. Hagari bí ọmọkunrin kan fún Abramu, Abramu sì sọ ọmọ náà ní Iṣimaeli. Abramu jẹ́ ẹni ọdún mẹrindinlaadọrun nígbà tí Hagari bí Iṣimaeli fún un. Nígbà tí Abramu di ẹni ọdún mọkandinlọgọrun-un, OLUWA farahàn án, ó sọ fún un pé, “Èmi ni Ọlọrun Olodumare, máa gbọ́ tèmi, kí o sì jẹ́ pípé. N óo bá ọ dá majẹmu kan, tí yóo wà láàrin èmi pẹlu rẹ, n óo sì bukun ọ lọpọlọpọ.” Abramu bá dojúbolẹ̀, Ọlọrun tún wí fún un pé, “Majẹmu tí mo bá ọ dá kò yẹ̀ rárá: O óo jẹ́ baba ńlá fún ọpọlọpọ orílẹ̀ èdè. Orúkọ rẹ kò ní jẹ́ Abramu mọ́, Abrahamu ni o óo máa jẹ́, nítorí mo ti sọ ọ́ di baba ńlá fún ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè. N óo sọ àwọn ọmọ rẹ di pupọ, n óo sì sọ ọ́ di ọpọlọpọ orílẹ̀ èdè, ọpọlọpọ ọba ni yóo sì ti ara rẹ jáde.” “N óo fìdí majẹmu mi múlẹ̀ láàrin èmi pẹlu rẹ, ati atọmọdọmọ rẹ. Majẹmu náà yóo wà títí ayérayé pé, èmi ni n óo máa jẹ́ Ọlọrun rẹ ati ti atọmọdọmọ rẹ. N óo fún ọ ní gbogbo ilẹ̀ Kenaani, ilẹ̀ náà tí o ti jẹ́ àlejò yìí yóo di ìní rẹ títí ayérayé ati ti atọmọdọmọ rẹ, n óo sì máa jẹ́ Ọlọrun wọn!” Ọlọrun tún sọ fún Abrahamu pé, “Ìwọ pàápàá gbọdọ̀ pa majẹmu mi mọ́, ìwọ ati atọmọdọmọ rẹ láti ìrandíran wọn. Majẹmu náà tí ó wà láàrin èmi pẹlu rẹ, ati atọmọdọmọ rẹ, tí ẹ gbọdọ̀ pamọ́ nìyí, gbogbo àwọn ọmọkunrin yín gbọdọ̀ kọlà abẹ́. Ilà abẹ́ tí ẹ gbọdọ̀ kọ yìí ni yóo jẹ́ àmì majẹmu tí ó wà láàrin mi pẹlu yín. Gbogbo ọmọkunrin tí ó bá ti pé ọmọ ọjọ́ mẹjọ láàrin yín gbọdọ̀ kọlà abẹ́, gbogbo ọmọkunrin ninu ìran yín, kì báà ṣe èyí tí a bí ninu ilé yín, tabi ẹrú tí ẹ rà lọ́wọ́ àjèjì, tí kì í ṣe ìran yín, gbogbo ọmọ tí ẹ bí ninu ilé yín, ati ẹrú tí ẹ fi owó yín rà gbọdọ̀ kọlà abẹ́. Èyí yóo jẹ́ kí majẹmu mi wà lára yín, yóo sì jẹ́ majẹmu ayérayé. Gbogbo ọkunrin tí kò bá kọlà abẹ́ ni a óo yọ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀, nítorí pé ó ti ba majẹmu mi jẹ́.” Ọlọrun sọ fún Abrahamu pé, “Ní ti Sarai aya rẹ, má ṣe pè é ní Sarai mọ́, Sara ni orúkọ rẹ̀ yóo máa jẹ́. N óo bukun un, n óo sì fún ọ ní ọmọkunrin kan láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, n óo bukun un, yóo sì di ìyá ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, ọpọlọpọ ọba ni yóo wà lára atọmọdọmọ rẹ̀.” Nígbà náà ni Abrahamu dojúbolẹ̀, ó búsẹ́rìn-ín, ó sì wí ninu ara rẹ̀ pé, “Ọkunrin tí ó ti di ẹni ọgọrun-un (100) ọdún ha tún lè bímọ bí? Sara, tí ó ti di ẹni aadọrun-un ọdún ha tún lè bímọ bí?” Abrahamu bá sọ fún Ọlọrun pé, “Ṣá ti bá mi dá Iṣimaeli yìí sí.” Ọlọrun dá a lóhùn, pé, “Rárá o, àní, Sara, aya rẹ, yóo bí ọmọkunrin kan fún ọ, o óo sọ ọmọ náà ní Isaaki. N óo fìdí majẹmu mi múlẹ̀ pẹlu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi majẹmu ayérayé fún atọmọdọmọ rẹ̀. Ní ti Iṣimaeli, mo ti gbọ́ ìbéèrè rẹ, wò ó, n óo bukun òun náà, n óo sì fún un ní ọpọlọpọ ọmọ ati ọmọ ọmọ, yóo jẹ́ baba fún àwọn ọba mejila, n óo sì sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńlá. Ṣugbọn n óo fìdí majẹmu mi múlẹ̀ pẹlu Isaaki, tí Sara yóo bí fún ọ ní ìwòyí ọdún tí ń bọ̀.” Nígbà tí Ọlọrun bá Abrahamu sọ̀rọ̀ tán, ó gòkè lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Abrahamu bá mú Iṣimaeli ọmọ rẹ̀, ati gbogbo àwọn ẹrukunrin tí wọ́n bí ninu ilé rẹ̀ ati àwọn tí ó fi owó rẹ̀ rà, àní gbogbo ọkunrin tí ó wà ninu ìdílé Abrahamu, ó sì kọ gbogbo wọn ní ilà abẹ́ ní ọjọ́ náà, bí Ọlọrun ti pàṣẹ fún un. Abrahamu jẹ́ ẹni ọdún mọkandinlọgọrun-un nígbà tí ó kọ ilà abẹ́. Iṣimaeli ọmọ rẹ̀ jẹ́ ọmọ ọdún mẹtala nígbà tí òun náà kọlà abẹ́. Ní ọjọ́ náà gan-an ni Abrahamu ati Iṣimaeli ọmọ rẹ̀ kọlà abẹ́, ati gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ninu ilé rẹ̀, ati àwọn tí wọ́n bí sinu ilé rẹ̀, ati àwọn tí wọ́n fi owó rà, gbogbo wọn ni wọ́n kọ nílà abẹ́ pẹlu rẹ̀. Ní ọ̀sán gangan ọjọ́ kan, OLUWA fara han Abrahamu bí ó ti jókòó ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ rẹ̀, lẹ́bàá igi Oaku ti Mamure. Bí ó ti gbójú sókè, bẹ́ẹ̀ ni ó rí àwọn ọkunrin mẹta kan, wọ́n dúró ní ọ̀kánkán níwájú rẹ̀. Bí ó ti rí wọn, ó sáré lọ pàdé wọn, ó wólẹ̀, ó sì dojúbolẹ̀ láti kí wọn. Ó wí pé, “Ẹ̀yin oluwa mi, bí inú yín bá dùn sí mi, ẹ jọ̀wọ́, ẹ má kọjá lọ bẹ́ẹ̀ láìdúró díẹ̀ lọ́dọ̀ èmi iranṣẹ yín! Ẹ jẹ́ kí wọ́n bu omi wá kí ẹ fi ṣan ẹsẹ̀, kí ẹ sì sinmi díẹ̀ lábẹ́ igi níhìn-ín. Níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti yà lọ́dọ̀ èmi iranṣẹ yín, ẹ kúkú jẹ́ kí n tètè tọ́jú oúnjẹ díẹ̀ fún yín láti jẹ, bí ẹ bá tilẹ̀ wá fẹ́ máa lọ nígbà náà, kò burú.” Wọ́n bá dá a lóhùn pé, “Ó dára, lọ ṣe bí o ti wí.” Abrahamu yára wọ inú àgọ́ tọ Sara lọ, ó sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ tètè tọ́jú ìwọ̀n ìyẹ̀fun dáradára mẹta, bá mi yára pò ó, kí o fi ṣe àkàrà.” Abrahamu tún yára lọ sinu agbo mààlúù rẹ̀, ó mú ọ̀dọ́ mààlúù kan tí ó lọ́ràá dáradára, ó fà á fún àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó ní kí wọ́n yára pa á, kí wọ́n sì sè é. Ó mú wàràǹkàṣì, ati omi wàrà, ati ẹran ọ̀dọ́ mààlúù tí wọ́n sè, ó gbé wọn kalẹ̀ fún àwọn àlejò náà, ó sì dúró tì wọ́n bí wọ́n ti ń jẹun lábẹ́ igi. Nígbà tí wọ́n jẹun tán, wọ́n bi í pé, “Níbo ni Sara aya rẹ wà?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Ó wà ninu àgọ́.” Ọ̀kan ninu àwọn àlejò náà wí pé, “Dájúdájú, n óo pada tọ̀ ọ́ wá ní ìwòyí ọdún tí ń bọ̀, Sara, aya rẹ yóo bí ọmọkunrin kan.” Sara fetí mọ́ ògiri lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ lẹ́yìn ibi tí àwọn àlejò náà wà, ó ń gbọ́ gbogbo ohun tí wọ́n ń sọ. Abrahamu ati Sara ti di àgbàlagbà ní àkókò yìí, ogbó ti dé sí wọn, ọjọ́ ti pẹ́ tí Sara ti rí nǹkan oṣù rẹ̀ kẹ́yìn. Nítorí náà, nígbà tí Sara gbọ́ pé òun óo bímọ, ó rẹ́rìn-ín sinu ara rẹ̀, ó ní, “Lẹ́yìn ìgbà tí mo ti di arúgbó, tí ọkọ mi náà sì ti di arúgbó, ǹjẹ́ mo tilẹ̀ tún lè gbádùn oorun ọmọ bíbí?” OLUWA bi Abrahamu pé, “Èéṣe tí Sara fi rẹ́rìn-ín, tí ó wí pé, ṣé lóòótọ́ ni òun óo bímọ lẹ́yìn tí òun ti darúgbó? Ṣé ohun kan wà tí ó ṣòro fún OLUWA ni? Nígbà tí àkókò bá tó, n óo pada wá sọ́dọ̀ rẹ níwòyí ọdún tí ń bọ̀, Sara yóo bí ọmọkunrin kan.” Ẹ̀rù ba Sara, ó sẹ́ pé òun kò rẹ́rìn-ín. OLUWA sọ pé, “Má purọ́! o rẹ́rìn-ín.” Nígbà tí àwọn ọkunrin náà kúrò lọ́dọ̀ Abrahamu, wọ́n dojú kọ ọ̀nà Sodomu, Abrahamu bá wọn lọ láti sìn wọ́n dé ọ̀nà. OLUWA sọ pé, “Mo ha gbọdọ̀ fi ohun tí mo fẹ́ ṣe yìí pamọ́ fún Abrahamu, nígbà tí ó jẹ́ pé ìran rẹ̀ yóo di orílẹ̀-èdè ńlá tí yóo lágbára, ati pé nípasẹ̀ rẹ̀ ni n óo bukun gbogbo orílẹ̀-èdè? N kò ní fi pamọ́ fún un, nítorí pé mo ti yàn án, kí ó lè pàṣẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀, ati gbogbo ará ilé rẹ̀, láti máa pa ìlànà èmi OLUWA mọ́, ati kí wọ́n sì jẹ́ olódodo ati olóòótọ́, kí èmi OLUWA lè mú ìlérí mi ṣẹ fún Abrahamu.” OLUWA bá sọ pé; “Ẹ̀sùn tí àwọn eniyan fi ń kan Sodomu ati Gomora ti pọ̀ jù, ẹ̀ṣẹ̀ wọn burú jáì! Mo fẹ́ lọ fi ojú ara mi rí i, kí n fi mọ̀, bóyá gbogbo bí mo ti ń gbọ́ nípa wọn ni wọ́n ń ṣe nítòótọ́.” Àwọn ọkunrin náà bá kúrò níbẹ̀, wọ́n gba ọ̀nà Sodomu lọ, ṣugbọn Abrahamu tún dúró níwájú OLUWA níbẹ̀. Abrahamu bá súnmọ́ OLUWA, ó wí pé, “O ha gbọdọ̀ pa àwọn olódodo run pẹlu àwọn eniyan burúkú bí? A kì í bàá mọ̀, bí aadọta olódodo bá wà ninu ìlú náà, ṣé o óo pa ìlú náà run, o kò sì ní dá a sí nítorí aadọta olódodo tí ó wà ninu rẹ̀? Kí á má rí i pé o ṣe irú ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀! Kí o pa olódodo run pẹlu àwọn eniyan burúkú? Ṣé kò ní sí ìyàtọ̀ láàrin ìpín àwọn eniyan burúkú ati ti àwọn olódodo ni? A kò gbọdọ̀ gbọ́ ọ. Ìwọ onídàájọ́ gbogbo ayé kò ha ní ṣe ẹ̀tọ́ bí?” OLUWA dáhùn, ó ní, “Bí mo bá rí aadọta olódodo ninu ìlú Sodomu, n óo dá gbogbo ìlú náà sí nítorí tiwọn.” Abrahamu tún sọ fún OLUWA pé, “Jọ̀wọ́, dárí àfojúdi mi jì mí, èmi eniyan lásán, nítorí n kò ní ẹ̀tọ́ láti bá ìwọ OLUWA jiyàn? Ṣugbọn, ó ṣeéṣe pé aadọta tí mo wí lè dín marun-un, ṣé nítorí eniyan marun-un tí ó dín, o óo pa ìlú náà run?” OLUWA dáhùn pé, “Bí mo bá rí olódodo marundinlaadọta n kò ní pa ìlú náà run.” Ó tún bèèrè pé, “Bí a bá rí ogoji ńkọ́?” OLUWA tún dáhùn, ó ní, “N kò ní pa á run nítorí ogoji eniyan náà.” Ó bá tún wí pé, “OLUWA, jọ̀wọ́ má bínú sí mi, bí a bá rí ọgbọ̀n eniyan ńkọ́?” OLUWA dáhùn pé, “Bí mo bá rí ọgbọ̀n olódodo, n kò ní pa ìlú náà run.” Ó tún dáhùn pé “Jọ̀wọ́ dárí àfojúdi mi jì mí nítorí ọ̀rọ̀ mi, bí a bá rí ogún eniyan ńkọ́?” OLUWA tún dáhùn pé, “Nítorí ti ogún eniyan, n kò ní pa á run.” Abrahamu tún dáhùn pé, “OLUWA, jọ̀wọ́ má bínú sí mi, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo péré yìí ni ó kù tí n óo sọ̀rọ̀. Bí a bá rí eniyan mẹ́wàá ńkọ́?” OLUWA tún dá a lóhùn pé, “N kò ní pa á run nítorí ti eniyan mẹ́wàá.” Nígbà tí OLUWA bá Abrahamu sọ̀rọ̀ tán, ó bá tirẹ̀ lọ, Abrahamu náà bá pada sí ilé rẹ̀. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà ni àwọn angẹli meji náà dé ìlú Sodomu, Lọti sì jókòó ní ẹnubodè ìlú náà. Bí ó ti rí wọn, ó dìde lọ pàdé wọn, ó wólẹ̀, ó sì dojúbolẹ̀ láti kí wọn. Ó ní, “Ẹ̀yin oluwa mi, ẹ jọ̀wọ́ ẹ yà sí ilé èmi iranṣẹ yín, kí ẹ ṣan ẹsẹ̀ yín, kí ẹ sì sùn ní alẹ́ yìí, bí ó bá di ìdájí ọ̀la, kí ẹ máa bá tiyín lọ.” Ṣugbọn wọ́n dáhùn pé, “Ó tì o! ìta gbangba láàrin ìlú ni a fẹ́ sùn.” Ṣugbọn ó rọ̀ wọ́n gidigidi, wọ́n bá yà sí ilé rẹ̀, ó se àsè fún wọn, ó ṣe àkàrà tí a kò fi ìwúkàrà sí, wọ́n sì jẹun. Ṣugbọn kí àwọn àlejò náà tó sùn, gbogbo àwọn ọkunrin ìlú Sodomu ti dé, àtèwe, àtàgbà, gbogbo wọn dé láìku ẹnìkan, wọ́n yí ilé Lọti po. Wọ́n pe Lọti, wọ́n ní, “Níbo ni àwọn ọkunrin tí wọ́n dé sọ́dọ̀ rẹ ní alẹ́ yìí wà? Kó wọn jáde fún wa, a fẹ́ bá wọn lòpọ̀.” Lọti bá jáde sí wọn, ó ti ìlẹ̀kùn mọ́ àwọn àlejò sinu ilé, ó bẹ̀ wọ́n pé, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ̀yin arakunrin mi, ẹ má hu irú ìwà burúkú yìí. Ẹ wò ó, mo ní àwọn ọmọbinrin meji tí wọn kò tíì mọ ọkunrin, ẹ jẹ́ kí n kó wọn jáde fún yín, kí ẹ ṣe wọ́n bí ó ti wù yín, ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi àwọn ọkunrin wọnyi sílẹ̀, nítorí pé inú ilé mi ni wọ́n wọ̀ sí.” Wọ́n dáhùn pé, “Yàgò lọ́nà fún wa, ṣebí àjèjì ni ọ́ ní ilẹ̀ yìí? Ta ni ọ́ tí o fi ń sọ ohun tí ó yẹ kí á ṣe fún wa? Bí o kò bá ṣọ́ra, a óo ṣe sí ọ ju bí a ti fẹ́ ṣe sí wọn lọ.” Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ti Lọti mọ́ ara ìlẹ̀kùn títí ìlẹ̀kùn fi fẹ́rẹ̀ já. Àwọn àjèjì náà bá fa Lọti wọlé, wọ́n ti ìlẹ̀kùn, wọ́n sì bu ìfọ́jú lu àwọn ọkunrin tí wọ́n ṣù bo ìlẹ̀kùn lóde, àtèwe, àtàgbà wọn, wọ́n wá ojú ọ̀nà títí tí agara fi dá wọn. Àwọn àlejò náà pe Lọti, wọ́n sọ fún un pé, “Bí o bá ní ẹnikẹ́ni ninu ìlú yìí, ìbáà ṣe ọmọkunrin tabi ọmọbinrin tabi ọkọ àwọn ọmọ rẹ, tabi ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ tìrẹ ninu ìlú yìí, kó wọn jáde kúrò níhìn-ín, nítorí pé a ti ṣetán láti pa ìlú yìí run, nítorí ẹ̀sùn tí wọ́n fi ń kan àwọn ará ìlú yìí ti pọ̀ níwájú OLUWA, OLUWA sì ti rán wa láti pa á run.” Lọti bá jáde lọ bá àwọn ọkunrin tí wọ́n fẹ́ àwọn ọmọbinrin rẹ̀ mejeeji sọ́nà, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ dìde, ẹ jáde kúrò ninu ìlú yìí nítorí OLUWA fẹ́ pa á run.” Ṣugbọn àwàdà ni ọ̀rọ̀ náà jọ létí wọn. Nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́jú, àwọn angẹli náà rọ Lọti pé, “Dìde, mú aya rẹ ati àwọn ọmọ rẹ mejeeji tí wọ́n wà níhìn-ín kí o sì jáde, kí o má baà parun pẹlu ìlú yìí.” Ṣugbọn nígbà tí Lọti bẹ̀rẹ̀ sí lọ́ra, àwọn angẹli meji náà mú òun ati aya rẹ̀, pẹlu àwọn ọmọbinrin rẹ̀ mejeeji, wọ́n kó wọn jáde lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú, nítorí pé OLUWA ṣàánú Lọti. Nígbà tí wọ́n kó wọn jáde tán, wọ́n wí fún wọn pé, “Ẹ sá àsálà fún ẹ̀mí yín; ẹ má ṣe wo ẹ̀yìn rárá, ẹ má sì ṣe dúró níbikíbi ní àfonífojì yìí, ẹ sá gun orí òkè lọ, kí ẹ má baà parun.” Ṣugbọn Lọti wí fún wọn pé, “Áà! Rárá! oluwa mi. Èmi iranṣẹ yín ti rí ojurere lọ́dọ̀ yín, ẹ sì ti ṣe mí lóore ńlá nípa gbígba ẹ̀mí mi là, ṣugbọn n kò ní le sálọ sí orí òkè, kí ijamba má baà ká mi mọ́ ojú ọ̀nà, kí n sì kú. Ẹ wò ó, ìlú tí ó wà lọ́hùn-ún nì súnmọ́ tòsí tó láti sálọ, ó sì tún jẹ́ ìlú kékeré. Ẹ jẹ́ kí n sálọ sibẹ, ṣebí ìlú kékeré ni? Ẹ̀mí mi yóo sì là.” OLUWA dáhùn pé, “Ó dára, mo gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ, n kò ní pa ìlú náà run. Ṣe kíá, kí o sálọ sibẹ, nítorí n kò lè ṣe ohunkohun, títí tí o óo fi dé ibẹ̀.” Nítorí náà ni wọ́n ṣe sọ ìlú náà ní Soari. Oòrùn ti yọ nígbà tí Lọti dé Soari. OLUWA bá rọ òjò imí ọjọ́ ati iná láti ọ̀run wá sórí Sodomu ati Gomora, ó sì pa ìlú náà run ati gbogbo àfonífojì náà. Ó pa gbogbo àwọn tí wọn ń gbé àwọn ìlú náà run, ati gbogbo ohun tí ó hù lórí ilẹ̀. Ṣugbọn aya Lọti tí ó wà lẹ́yìn ọkọ rẹ̀ wo ẹ̀yìn, ó sì di ọ̀wọ̀n iyọ̀. Nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́jú Abrahamu lọ sí ibi tí ó ti dúró níwájú OLUWA, ó wo ìhà ibi tí Sodomu ati Gomora wà, ati gbogbo àfonífojì náà, ó rí i pé gbogbo rẹ̀ ń yọ èéfín bí iná ìléru ńlá. Ọlọrun ranti Abrahamu, nígbà tí ó pa àwọn ìlú tí ó wà ní àfonífojì náà, níbi tí Lọti ń gbé run, ó yọ Lọti jáde kúrò ninu ìparun. Nígbà tí ó yá, Lọti jáde kúrò ní Soari, nítorí ẹ̀rù ń bà á láti máa gbé ibẹ̀, òun ati àwọn ọmọbinrin rẹ̀ mejeeji bá kó lọ sí orí òkè, wọ́n sì ń gbé inú ihò kan níbẹ̀. Ní ọjọ́ kan, èyí ẹ̀gbọ́n wí fún àbúrò, ó ní, “Baba wa ń darúgbó lọ, kò sì sí ọkunrin kan tí yóo fẹ́ wa gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwọn eniyan. Wò ó! Jẹ́ kí á mú baba wa mu ọtí àmupara, kí á sì sùn lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó lè bá wa lòpọ̀, kí á le tipasẹ̀ rẹ̀ bímọ.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe fún baba wọn ní ọtí mu ní alẹ́ ọjọ́ náà, èyí àkọ́bí wọlé lọ, ó sì mú kí baba wọ́n bá òun lòpọ̀, baba wọn kò mọ ìgbà tí ó sùn ti òun, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ ìgbà tí ó dìde. Ní ọjọ́ keji, èyí àkọ́bí sọ fún àbúrò pé, “Èmi ni mo sùn lọ́dọ̀ baba wa lánàá, jẹ́ kí á tún mú kí ó mu ọtí àmupara lálẹ́ òní, kí ìwọ náà lè wọlé tọ̀ ọ́ lọ, kí ó lè bá ọ lòpọ̀, kí á sì lè bímọ nípasẹ̀ baba wa.” Wọ́n mú kí baba wọn mu ọtí waini ní alẹ́ ọjọ́ náà pẹlu, èyí àbúrò lọ sùn tì í, baba wọn kò mọ ìgbà tí ó sùn ti òun, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ ìgbà tí ó dìde. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Lọti mejeeji ṣe lóyún fún baba wọn. Èyí àkọ́bí bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọ́ ní Moabu, òun ni baba ńlá àwọn ẹ̀yà Moabu títí di òní olónìí. Èyí àbúrò náà bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọ́ ní Bẹnami, òun ni baba ńlá àwọn ẹ̀yà Amoni títí di òní olónìí. Láti ibẹ̀ ni Abrahamu ti lọ sí agbègbè Nẹgẹbu, ó sì ń gbé Gerari, ní ààrin Kadeṣi ati Ṣuri. Abrahamu sọ fún àwọn ará Gerari pé arabinrin òun ni Sara aya rẹ̀, Abimeleki, ọba Gerari bá ranṣẹ lọ mú Sara. Ṣugbọn Ọlọrun tọ Abimeleki wá lóru lójú àlá, ó sì wí fún un pé, “O jẹ́ mọ̀! Ikú ti pa ọ́ tán báyìí, nítorí pé obinrin tí o mú sọ́dọ̀, aya aláya ni.” Ṣugbọn Abimeleki kò tíì bá Sara lòpọ̀ rárá, ó bá bèèrè lọ́wọ́ OLUWA pé, “OLUWA, o wá lè pa àwọn eniyan aláìṣẹ̀ bí? Ṣebí ẹnu ara rẹ̀ ni ó fi sọ pé arabinrin òun ni, tí obinrin náà sì sọ pé arakunrin òun ni. Ohun tí mo ṣe tí ó di ẹ̀ṣẹ̀ yìí, òtítọ́ inú ati àìmọ̀ ni mo fi ṣe é.” Ọlọrun dá a lóhùn lójú àlá, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ pé òtítọ́ inú ni o fi ṣe ohun tí o ṣe, èmi ni mo sì pa ọ́ mọ́ tí n kò jẹ́ kí o ṣẹ̀ mí, ìdí sì nìyí tí n kò fi jẹ́ kí o fọwọ́ kàn án. Ǹjẹ́ nisinsinyii, dá obinrin náà pada fún ọkọ rẹ̀, nítorí pé wolii ni ọkunrin náà yóo gbadura fún ọ, o óo sì yè. Ṣugbọn bí o kò bá dá a pada, mọ̀ dájú pé o óo kú, àtìwọ ati gbogbo àwọn eniyan rẹ.” Abimeleki yára dìde ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, ó pe gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀ jọ, ó ro gbogbo nǹkan wọnyi fún wọn, ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi. Abimeleki bá pe Abrahamu, ó bi í pé, “Kí ló dé tí o fi ṣe wá báyìí? Irú ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ ọ́ tí o fi ti ẹ̀ṣẹ̀ ńlá yìí sí èmi ati ìjọba mi lọ́rùn? Ohun tí o ṣe sí mi yìí kò dára rárá!” Ó bi Abrahamu pé, “Kí ni èrò rẹ gan-an, tí o fi ṣe ohun tí o ṣe yìí?” Abrahamu dáhùn, ó ní, “Ohun tí ó mú mi sọ bẹ́ẹ̀ ni pé, mo rò pé kò sí ìbẹ̀rù Ọlọrun níhìn-ín rárá ni, ati pé wọn yóo tìtorí aya mi pa mí. Ati pé, arabinrin mi ni nítòótọ́, bí ó ṣe jẹ́ nìyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ìyá kan náà ni ó bí wa, ọmọ baba kan ni wá kí ó tó di aya mi. Nígbà tí Ọlọrun mú kí n máa káàkiri kúrò ní ilé baba mi, mo wí fún un pé, ‘Oore kan tí o lè ṣe fún mi nìyí: níbi gbogbo tí a bá dé, wí fún wọn pé, arakunrin rẹ ni mí.’ ” Abimeleki mú aguntan ati mààlúù ati ẹrukunrin ati ẹrubinrin, ó kó wọn fún Abrahamu, ó sì dá Sara, aya rẹ̀, pada fún un. Abimeleki tún wí fún un pé, “Wo gbogbo ilẹ̀ yìí, èmi ni mo ni ín, yan ibi tí ó bá wù ọ́ láti gbé.” Ó wí fún Sara náà pé, “Mo ti kó ẹgbẹrun (1,000) owó fadaka fún arakunrin rẹ, èyí ni láti wẹ̀ ọ́ mọ́ lójú gbogbo àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ, nisinsinyii, o ti gba ìdáláre lójú gbogbo eniyan.” Abrahamu bá gbadura sí Ọlọrun, Ọlọrun sì wo Abimeleki sàn ati aya rẹ̀ ati àwọn ẹrubinrin rẹ̀, tí wọ́n fi lè bímọ, nítorí pé Ọlọrun ti sé gbogbo àwọn obinrin ilé Abimeleki ninu nítorí Sara, aya Abrahamu. OLUWA bẹ Sara wò gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, ó sì ṣe fún un gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀. Sara lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan fún Abrahamu lẹ́yìn tí ó ti di arúgbó, ní àkókò tí Ọlọrun sọ fún un. Abrahamu sọ ọmọkunrin náà ní Isaaki. Ó kọlà abẹ́ fún ọmọ náà nígbà tí ó di ọmọ ọjọ́ kẹjọ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pàṣẹ fún un. Abrahamu jẹ́ ẹni ọgọrun-un (100) ọdún nígbà tí a bí Isaaki fún un. Sara wí pé, “Ọlọ́run ti pa mí lẹ́rìn-ín, gbogbo ẹni tí ó bá gbọ́ ni yóo sì rẹ́rìn-ín.” Ó tún wí pé, “Ta ni ó lè sọ fún Abrahamu pé Sara yóo fún ọmọ lọ́mú? Sibẹsibẹ mo bí ọmọ fún un nígbà tí ó ti di arúgbó.” Ọmọ náà dàgbà, ó sì já lẹ́nu ọmú, Abrahamu sì se àsè ńlá ní ọjọ́ tí ọmọ náà já lẹ́nu ọmú. Ní ọjọ́ kan, Sara rí ọmọ tí Hagari, ará Ijipti bí fún Abrahamu, níbi tí ó ti ń bá Isaaki, ọmọ rẹ̀, ṣeré. Sara bá pe Abrahamu, ó sọ fún un pé, “Lé ẹrubinrin yìí jáde pẹlu ọmọ rẹ̀, nítorí pé ọmọ ẹrubinrin yìí kò ní jẹ́ àrólé pẹlu Isaaki ọmọ mi.” Ọ̀rọ̀ yìí kò dùn mọ́ Abrahamu ninu nítorí Iṣimaeli, ọmọ rẹ̀. Ṣugbọn Ọlọrun wí fún Abrahamu pé, “Má ṣe jẹ́ kí inú rẹ bàjẹ́ nítorí ọ̀rọ̀ ọmọ yìí ati ti ẹrubinrin rẹ, ohunkohun tí Sara bá wí fún ọ ni kí o ṣe, nítorí pé orúkọ Isaaki ni wọn yóo fi máa pe atọmọdọmọ rẹ. N óo sọ ọmọ ẹrubinrin náà di orílẹ̀ èdè ńlá pẹlu, nítorí ọmọ rẹ ni òun náà.” Abrahamu bá dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, ó mú oúnjẹ ati omi sinu ìgò aláwọ kan, ó dì wọ́n fún Hagari, ó kó wọn kọ́ ọ léjìká, ó fa ọmọ rẹ̀ lé e lọ́wọ́, ó ní kí wọn ó jáde kúrò nílé. Hagari jáde nílé, ó bá ń rìn káàkiri ninu aginjù Beeriṣeba. Nígbà tí omi tán ninu ìgò aláwọ náà, Hagari fi ọmọ náà sílẹ̀ lábẹ́ igbó ṣúúrú kan tí ó wà níbẹ̀. Ó lọ jókòó ní òkèèrè, ó takété sí i, ó tó ìwọ̀n ibi tí ọfà tí eniyan bá ta lè balẹ̀ sí, nítorí ó wí ninu ara rẹ̀ pé, “Má jẹ́ kí n wo àtikú ọmọ mi.” Bí ó ṣe jókòó tí ó takété sí ọmọ náà, ọmọ fi igbe ta, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọkún. Ọlọrun gbọ́ igbe ọmọ náà, angẹli Ọlọrun bá ké sí Hagari láti ọ̀run wá, ó bi í pé, “Kí ni ó ń dààmú ọkàn rẹ, Hagari? Má bẹ̀rù, nítorí Ọlọrun ti gbọ́ ẹkún ọmọ náà níbi tí ó wà. Dìde, lọ gbé e, kí o sì rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún, nítorí n óo sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá.” Ọlọrun bá la Hagari lójú, ó rí kànga kan, ó rọ omi kún inú ìgò aláwọ rẹ̀, ó sì fún ọmọdekunrin náà mu. Ọlọrun wà pẹlu ọmọ náà, ó dàgbà, ó ń gbé ninu aginjù, ó sì mọ ọfà ta tóbẹ́ẹ̀ tí ó di atamátàsé. Ó ń gbé inú aginjù Parani, ìyá rẹ̀ sì fẹ́ aya fún un ní ilẹ̀ Ijipti. Ní àkókò náà, Abimeleki ati Fikoli, olórí ogun rẹ̀, sọ fún Abrahamu pé, “Ọlọrun wà pẹlu rẹ ninu ohun gbogbo tí ò ń ṣe. Nítorí náà, fi Ọlọrun búra fún mi níhìn-ín yìí, pé o kò ní hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí mi, tabi sí àwọn ọmọ mi, tabi sí ìran mi, ṣugbọn bí mo ti jẹ́ olóòótọ́ sí ọ, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ náà yóo jẹ́ olóòótọ́ sí mi ati sí ilẹ̀ tí o ti ń ṣe àtìpó.” Abrahamu bá sọ pé òun yóo búra. Abrahamu rò fún Abimeleki bí àwọn iranṣẹ Abimeleki ti fi ipá gba kànga omi kan lọ́wọ́ rẹ̀, Abimeleki bá dá a lóhùn, ó ní “N kò mọ ẹni tí ó ṣe bẹ́ẹ̀, o kò sọ fún mi, n kò gbọ́ nǹkankan nípa rẹ̀, àfi bí o ti ń sọ yìí.” Abrahamu fún Abimeleki ní aguntan ati mààlúù, àwọn mejeeji bá jọ dá majẹmu. Abrahamu ya abo ọmọ aguntan meje ninu agbo rẹ̀ sọ́tọ̀. Abimeleki bá bi Abrahamu, ó ní, “Kí ni ìtumọ̀ abo ọmọ aguntan meje tí o yà sọ́tọ̀ wọnyi?” Abrahamu dá a lóhùn pé, “Gba abo ọmọ aguntan meje wọnyi lọ́wọ́ mi, kí o lè jẹ́ ẹlẹ́rìí mi pé èmi ni mo gbẹ́ kànga yìí.” Ìdí rẹ̀ nìyí tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní Beeriṣeba, nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn mejeeji ti búra. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe dá majẹmu ní Beeriṣeba. Abimeleki ati Fikoli, olórí ogun rẹ̀, sì pada lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Filistia. Abrahamu gbin igi tamarisiki kan sí Beeriṣeba, ó sì ń sin OLUWA Ọlọrun ayérayé níbẹ̀. Abrahamu gbé ilẹ̀ àwọn ará Filistia fún ìgbà pípẹ́. Lẹ́yìn nǹkan wọnyi, Ọlọrun dán Abrahamu wò, ó ní, “Abrahamu!” Abrahamu dáhùn pé, “Èmi nìyí.” Ọlọrun ní, “Mú Isaaki ọmọ rẹ kan ṣoṣo tí o fẹ́ràn, kí o lọ sí ilẹ̀ Moraya, kí o sì fi ọmọ náà rú ẹbọ sísun lórí ọ̀kan ninu àwọn òkè tí n óo júwe fún ọ.” Abrahamu bá dìde ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, ó di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó mú meji ninu àwọn ọdọmọkunrin ilé rẹ̀, ati Isaaki ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́. Ó gé igi fún ẹbọ sísun, lẹ́yìn náà wọ́n gbéra, wọ́n lọ sí ibi tí Ọlọrun ti júwe fún Abrahamu. Ní ọjọ́ kẹta, bí Abrahamu ti wo ọ̀kánkán, ó rí ibi tí Ọlọrun júwe fún un ní òkèèrè. Abrahamu bá sọ fún àwọn ọdọmọkunrin tí wọ́n tẹ̀lé e, ó ní, “Ẹ dúró ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ níhìn-ín, èmi ati ọmọ yìí yóo rìn siwaju díẹ̀, láti lọ sin Ọlọ́run, a óo sì pada wá bá yín.” Abrahamu gbé igi ẹbọ sísun náà lé Isaaki, ọmọ rẹ̀ lórí, ó mú ọ̀bẹ ati iná lọ́wọ́. Àwọn mejeeji jọ ń lọ. Isaaki bá pe Abrahamu, baba rẹ̀, ó ní, “Baba mi.” Baba rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Kí ni, ọmọ mi?” Isaaki ní, “Wò ó, a rí iná ati igi, àgbò tí a óo fi rú ẹbọ sísun dà?” Abrahamu dá a lóhùn pé, “Ọmọ mi, Ọlọrun fúnrarẹ̀ ni yóo pèsè, àgbò tí a óo fi rú ẹbọ sísun náà.” Àwọn mejeeji tún ń bá ìrìn àjò wọn lọ. Nígbà tí wọ́n dé ibi tí Ọlọrun júwe fún Abrahamu, ó tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀, ó to igi sórí pẹpẹ náà, ó di Isaaki ọmọ rẹ̀ tọwọ́ tẹsẹ̀, ó bá gbé e ka orí igi lórí pẹpẹ tí ó tẹ́. Abrahamu nawọ́ mú ọ̀bẹ láti pa ọmọ rẹ̀. Ṣugbọn angẹli OLUWA pè é láti òkè ọ̀run, ó ní, “Abrahamu! Abrahamu!” Abrahamu dáhùn, ó ní, “Èmi nìyí.” Angẹli náà wí fún un pé, “Má ṣe pa ọmọ náà rárá, má sì ṣe é ní ohunkohun, nítorí pé nisinsinyii mo mọ̀ dájú pé o bẹ̀rù Ọlọrun, nígbà tí o kò kọ̀ láti fi ọmọ rẹ kan ṣoṣo tí o bí rúbọ sí èmi Ọlọrun.” Bí Abrahamu ti gbé orí sókè, tí ó wo ẹ̀yìn rẹ̀, ó rí àgbò kan tí ó fi ìwo kọ́ pàǹtí. Ó lọ mú àgbò náà, ó sì fi rú ẹbọ sísun dípò ọmọ rẹ̀. Nítorí náà ni Abrahamu ṣe sọ ibẹ̀ ní “OLUWA yóo pèsè,” bí wọ́n ti ń wí títí di òní, pé, “Ní orí òkè OLUWA ni yóo ti pèsè.” Angẹli OLUWA tún pe Abrahamu láti òkè ọ̀run ní ìgbà keji, ó ní, “Mo fi ara mi búra pé nítorí ohun tí o ṣe yìí, tí o kò kọ̀ láti fún mi ní ọmọ rẹ kan ṣoṣo, n óo bukun ọ lọpọlọpọ, n óo sọ àwọn ọmọ ọmọ rẹ di pupọ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ati bíi yanrìn etí òkun. Àwọn ọmọ ọmọ rẹ yóo máa ṣẹgun àwọn ọ̀tá wọn ní gbogbo ìgbà. Nípasẹ̀ àwọn ọmọ rẹ ni n óo ti bukun gbogbo orílẹ̀-èdè ayé, nítorí pé o gbọ́ràn sí mi lẹ́nu.” Abrahamu bá pada tọ àwọn ọdọmọkunrin rẹ̀ lọ, wọ́n bá jọ gbéra, wọ́n pada lọ sí Beeriṣeba, Abrahamu sì ń gbé ibẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n wá sọ fún Abrahamu pé Milika ti bímọ fún Nahori arakunrin rẹ̀. Usi ni àkọ́bí, Busi ni wọ́n bí tẹ̀lé e, lẹ́yìn náà Kemueli tíí ṣe baba Aramu. Lẹ́yìn rẹ̀ ni wọ́n bí Kesedi, Haso, Pilidaṣi, Jidilafi ati Betueli. Betueli ni baba Rebeka. Àwọn mẹjẹẹjọ yìí ni Milika bí fún Nahori, arakunrin Abrahamu. Nahori tún ní obinrin mìíràn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Reuma, òun ni ó bí Teba, Gahamu, Tahaṣi, ati Mahaka fún Nahori. Ọdún mẹtadinlaadoje (127) ni Sara gbé láyé. Ó kú ní Kiriati Ariba, ní Heburoni, ní ilẹ̀ Kenaani, Abrahamu sọkún, ó sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀. Nígbà tí ó yá, Abrahamu dìde níwájú òkú Sara, ó lọ bá àwọn ará Hiti, ó ní, “Àlejò ni mo jẹ́ láàrin yín, ẹ bá mi wá ilẹ̀ ní ìwọ̀nba ninu ilẹ̀ yín tí mo lè máa lò bí itẹ́ òkú, kí n lè sin òkú aya mi yìí, kí ó kúrò nílẹ̀.” Àwọn ará Hiti dá Abrahamu lóhùn, wọ́n ní, “Gbọ́, oluwa wa, olóyè pataki ni o jẹ́ láàrin wa. Sin òkú aya rẹ síbikíbi tí ó bá wù ọ́ jùlọ ninu àwọn itẹ́ òkú wa, kò sí ẹnikẹ́ni ninu wa tí kò ní fún ọ ní itẹ́ òkú rẹ̀, tabi tí yóo dí ọ lọ́wọ́, pé kí o má ṣe ohun tí o fẹ́ ṣe.” Abrahamu bá dìde, ó tẹríba níwájú wọn, ó ní, “Bí ẹ bá fẹ́ kí n sin òkú aya mi kúrò nílẹ̀ nítòótọ́, ẹ gbọ́ tèmi, kí ẹ sì bá mi sọ fún Efuroni ọmọ Sohari, kí ó fún mi ní ihò Makipela, òun ni ó ni ihò náà, ní ìpẹ̀kun ilẹ̀ rẹ̀ ni ó wà. Títà ni mo fẹ́ kí ó tà á fún mi ní iyekíye tí ilẹ̀ náà bá tó, lójú gbogbo yín, n óo sì lè máa lo ilẹ̀ náà bí itẹ́ òkú.” Efuroni alára wà ní ìjókòó pẹlu àwọn ará Hiti yòókù, lójú gbogbo àwọn ará ìlú náà ni ó ti dá Abrahamu lóhùn, ó ní, “Rárá o! oluwa mi, gbọ́, mo fún ọ ní ilẹ̀ náà, ati ihò tí ó wà ninu rẹ̀, lójú gbogbo àwọn eniyan mi ni mo sì ti fún ọ, lọ sin aya rẹ sibẹ.” Nígbà náà ni Abrahamu tẹríba níwájú gbogbo wọn. Ó bá sọ fún Efuroni lójú gbogbo wọn, ó ní, “Ṣugbọn, bí ó bá ti ọkàn rẹ wá, fún mi ní ilẹ̀ náà, kí n sì san owó rẹ̀ fún ọ. Gbà á lọ́wọ́ mi, kí n lè lọ sin aya mi sibẹ.” Efuroni dá Abrahamu lóhùn, ó ní, “Olúwa mi, gbọ́, ilẹ̀ yìí kò ju irinwo (400) ìwọ̀n ṣekeli fadaka lọ, èyí kò tó nǹkankan láàrin èmi pẹlu rẹ. Lọ sin òkú aya rẹ.” Abrahamu gbà bí Efuroni ti wí, ó bá wọn irinwo (400) ìwọ̀n ṣekeli fadaka tí Efuroni dárúkọ fún un lójú gbogbo wọn, ó lo ìwọ̀n tí àwọn oníṣòwò ìgbà náà ń lò. Bẹ́ẹ̀ ni ilẹ̀ Efuroni ní Makipela, tí ó wà ní apá ìhà ìlà oòrùn Mamure ṣe di ti Abrahamu, ati ihò tí ó wà ninu ilẹ̀ náà, ati gbogbo igi tí ó wà ninu rẹ̀ jákèjádò. Gbogbo àwọn ará Hiti tí wọ́n wà níbẹ̀ jẹ́rìí sí i pé ilẹ̀ náà di ti Abrahamu. Lẹ́yìn náà, Abrahamu lọ sin òkú Sara sinu ihò ilẹ̀ Makipela, tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn Mamure, ní agbègbè Heburoni ní ilẹ̀ Kenaani. Ilẹ̀ náà ati ihò tí ó wà ninu rẹ̀ ni àwọn ará Hiti fi fún Abrahamu láti máa lò bí itẹ́ òkú. Abrahamu ti darúgbó, Ọlọrun sì ti bukun un ní gbogbo ọ̀nà. Abrahamu sọ fún iranṣẹ rẹ̀ tí ó dàgbà jù ninu ilé rẹ̀, ẹni tí í ṣe alákòóso ohun gbogbo tí ó ní, pé, “Ti ọwọ́ rẹ bọ abẹ́ itan mi, n óo sì mú kí o búra ní orúkọ OLUWA Ọlọrun ọ̀run ati ayé, pé o kò ní fẹ́ aya fún ọmọ mi lára àwọn ọmọbinrin ará Kenaani tí mò ń gbé, ṣugbọn o óo lọ sí ìlú mi, lọ́dọ̀ àwọn ẹbí mi, láti fẹ́ aya fún Isaaki, ọmọ mi.” Iranṣẹ náà dá a lóhùn pé, “Bí ọmọbinrin náà bá kọ̀ láti bá mi wá sí ilẹ̀ yìí, ṣé kí n mú ọmọ rẹ pada sí ilẹ̀ tí o ti wá síhìn-ín?” Abrahamu dáhùn pé, “Rárá o! O kò gbọdọ̀ mú ọmọ mi pada sibẹ. OLUWA Ọlọrun ọ̀run, tí ó mú mi jáde láti ilé baba mi, ati ilẹ̀ tí wọ́n bí mi sí, tí ó bá mi sọ̀rọ̀, tí ó sì búra fún mi pé, àwọn ọmọ mi ni òun yóo fi ilẹ̀ yìí fún, yóo rán angẹli rẹ̀ ṣáájú rẹ, o óo sì fẹ́ aya wá fún ọmọ mi láti ibẹ̀. Ṣugbọn bí obinrin náà bá kọ̀ tí kò tẹ̀lé ọ, nígbà náà ọrùn rẹ yóo mọ́ ninu ìbúra tí o búra fún mi, ṣá má ti mú ọmọ mi pada sibẹ.” Iranṣẹ náà bá ti ọwọ́ rẹ̀ bọ abẹ́ itan Abrahamu oluwa rẹ̀, ó sì búra láti ṣe ohun tí Abrahamu pa láṣẹ fún un. Iranṣẹ náà mú mẹ́wàá ninu àwọn ràkúnmí oluwa rẹ̀, ó gba oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn àtàtà lọ́wọ́ oluwa rẹ̀, ó jáde lọ sí ilẹ̀ Mesopotamia, sí ìlú Nahori. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, ní déédé ìgbà tí àwọn obinrin máa ń jáde lọ pọn omi, ó mú kí àwọn ràkúnmí rẹ̀ kúnlẹ̀ lẹ́yìn odi ìlú lẹ́bàá kànga kan, ó sì gbadura báyìí pé “Ìwọ OLUWA Ọlọrun Abrahamu, oluwa mi, jọ̀wọ́, ṣe ọ̀nà mi ní rere lónìí, kí o sì fi ìfẹ́ ńlá rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí Abrahamu, oluwa mi. Bí mo ti dúró lẹ́bàá kànga yìí, tí àwọn ọdọmọbinrin ìlú yìí sì ń jáde wá láti pọn omi, jẹ́ kí ọmọbinrin tí mo bá sọ fún pé jọ̀wọ́ sọ ìkòkò omi rẹ kalẹ̀ kí o fún mi ní omi mu, tí ó sì dá mi lóhùn pé, ‘Omi nìyí, mu, n óo sì fún àwọn ràkúnmí rẹ mu pẹlu,’ jẹ́ kí olúwarẹ̀ jẹ́ ẹni náà tí o yàn fún Isaaki, iranṣẹ rẹ. Èyí ni n óo fi mọ̀ pé o ti fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí oluwa mi.” Kí ó tó dákẹ́ adura rẹ̀ ni Rebeka ọmọ Betueli yọ sí i pẹlu ìkòkò omi ní èjìká rẹ̀. Ọmọ Nahori ni Betueli jẹ́, tí Milika bí fún un. Nahori yìí jẹ́ arakunrin Abrahamu. Arẹwà wundia ni Rebeka, kò sì tíì mọ ọkunrin. Bí ó ti dé, ó sọ̀kalẹ̀ lọ sinu odò, ó pọn omi rẹ̀, ó sì jáde. Iranṣẹ Abrahamu bá sáré tẹ̀lé e, ó bẹ̀ ẹ́ pé, “Jọ̀wọ́ fún mi ní omi díẹ̀ mu ninu ìkòkò rẹ.” Ọmọbinrin náà dáhùn pé, “Omi nìyí, oluwa mi.” Ó sì yára gbé ìkòkò rẹ̀ lé ọwọ́ rẹ̀ láti fún un ní omi mu. Bí Rebeka ti fún un ní omi tán, ó ní, “Jẹ́ kí n pọn omi fún àwọn ràkúnmí rẹ pẹlu, títí tí gbogbo wọn yóo fi mu omi tán” Kíá, ó ti da omi tí ó kù ninu ìkòkò rẹ̀ sinu agbada tí ẹran fi ń mu omi, ó sáré pada lọ pọn sí i, títí tí gbogbo wọn fi mu omi káríkárí. Ọkunrin náà fọwọ́ lẹ́rán, ó ń wò pé bóyá lóòótọ́ ni OLUWA ti ṣe ọ̀nà òun ní rere ni tabi bẹ́ẹ̀ kọ́. Nígbà tí àwọn ràkúnmí rẹ̀ mu omi tán, tí gbogbo wọn yó, ọkunrin yìí fún un ní òrùka imú tí a fi wúrà ṣe, tí ó wọ̀n tó ìwọ̀n ìdajì ṣekeli, ati ẹ̀gbà ọwọ́ meji tí a fi wúrà ṣe tí ó wọ̀n tó ìwọ̀n ṣekeli wúrà mẹ́wàá. Lẹ́yìn náà, ó bi í pé, “Jọ̀wọ́, kí ni orúkọ baba rẹ? Ǹjẹ́ ààyè ṣì wà ní ilé yín tí a lè wọ̀ sí ní alẹ́ yìí?” Ó dá a lóhùn, ó ní, “Betueli, ọmọ tí Milika bí fún Nahori ni baba mi.” Ó tún fi kún un pé, “A ní ọpọlọpọ koríko ati oúnjẹ ẹran, ààyè sì wà láti sùn ní ilé wa.” Ọkunrin náà bá tẹríba, ó sì sin OLUWA, ó sọ pé, “Ọpẹ́ ni fún ọ OLUWA Ọlọrun Abrahamu, oluwa mi, tí kò gbàgbé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ati òdodo rẹ̀ sí oluwa mi. Ní tèmi, OLUWA ti tọ́ mi sọ́nà tààrà, sí ilé àwọn ìbátan oluwa mi.” Ọmọbinrin náà bá sáré lọ sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún àwọn ará ilé ìyá rẹ̀. Rebeka ní arakunrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Labani. Labani yìí ni ó sáré lọ bá ọkunrin náà ní ìdí kànga. Lẹ́yìn tí ó rí òrùka ati ẹ̀gbà ọwọ́ lọ́wọ́ arabinrin rẹ̀, tí ó sì ti gbọ́ ohun tí Rebeka sọ pé ọkunrin náà sọ fún òun, ó lọ bá ọkunrin náà níbi tí ó dúró sí lẹ́bàá kànga pẹlu àwọn ràkúnmí rẹ̀. Labani sọ fún un pé, “Jẹ́ kí á lọ sí ilé, ìwọ ẹni tí OLUWA bukun. Èéṣe tí o fi dúró níta gbangba? Mo ti tọ́jú ilé, mo sì ti pèsè ààyè sílẹ̀ fún àwọn ràkúnmí rẹ.” Ọkunrin náà bá wọlé, Labani sì tú gàárì àwọn ràkúnmí rẹ̀, ó fi koríko ati oúnjẹ fún wọn. Ó fún un ní omi láti fi ṣan ẹsẹ̀ rẹ̀ ati ẹsẹ̀ àwọn ọkunrin tí wọ́n bá a wá. Wọ́n gbé oúnjẹ wá fún un pé kí ó jẹ, ṣugbọn ó wí pé, “N kò ní jẹun títí n óo fi jíṣẹ́ tí wọ́n rán mi.” Labani dáhùn, ó ní, “À ń gbọ́.” Ọkunrin náà bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní, “Iranṣẹ Abrahamu ni mí, OLUWA ti bukun oluwa mi lọpọlọpọ, ó sì ti di eniyan ńlá. OLUWA ti fún un ní ọpọlọpọ mààlúù ati agbo ẹran, ọpọlọpọ fadaka ati wúrà, ọpọlọpọ iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, ati ọpọlọpọ ràkúnmí ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Sara, aya oluwa mi bí ọmọkunrin kan fún un lẹ́yìn tí ó ti di arúgbó, ọmọ yìí sì ni oluwa mi fi ohun gbogbo tí ó ní fún. Oluwa mi mú mi búra pé n kò gbọdọ̀ fẹ́ aya fún ọmọ òun láàrin àwọn ará ilẹ̀ Kenaani tí òun ń gbé. Ó ni mo gbọdọ̀ wá síhìn-ín, ní ilé baba òun ati sọ́dọ̀ àwọn ẹbí òun láti fẹ́ aya fún ọmọ òun. Mo sì bi oluwa mi nígbà náà pé, ‘bí obinrin náà bá kọ̀ láti bá mi wá ńkọ́?’ Ṣugbọn ó sọ fún mi pé, ‘OLUWA náà tí òun ń fi gbogbo ayé òun sìn yóo rán angẹli rẹ̀ sí mi, yóo sì ṣe ọ̀nà mi ní rere. Ó ní, mo ṣá gbọdọ̀ fẹ́ aya fún ọmọ òun láàrin àwọn eniyan òun ati ní ilé baba òun. Nígbà náà ni ọrùn mi yóo tó mọ́ kúrò ninu ìbúra tí mo bú fún òun. Bí mo bá dé ọ̀dọ̀ àwọn ìbátan òun, tí wọ́n bá kọ̀, tí wọn kò jẹ́ kí ọmọbinrin wọn bá mi wá, ọrùn mi yóo mọ́ kúrò ninu ìbúra tí mo bú.’ “Lónìí, bí mo ti dé ìdí kànga tí ó wà lẹ́yìn ìlú, bẹ́ẹ̀ ni mo gbadura sí Ọlọrun, mo ní, ‘OLUWA Ọlọrun Abrahamu, oluwa mi, bí ó bá jẹ́ pé o ti ṣe ọ̀nà mi ní rere nítòótọ́, bí mo ti dúró nídìí kànga yìí, ọmọbinrin tí ó bá wá pọnmi, tí mo bá sì sọ fún pé, jọ̀wọ́, fún mi lómi mu ninu ìkòkò omi rẹ, tí ó bá wí fún mi pé, “Omi nìyí, mu, n óo sì pọn fún àwọn ràkúnmí rẹ pẹlu”, nígbà náà ni n óo mọ̀ pé òun ni obinrin náà tí ìwọ OLUWA ti yàn láti jẹ́ aya ọmọ oluwa mi.’ Kí n tó dákẹ́ adura mi, Rebeka yọ pẹlu ìkòkò omi ní èjìká rẹ̀. Ó sọ̀kalẹ̀ lọ sinu odò, ó sì pọnmi. Mo bá wí fún un pé, ‘Jọ̀wọ́ fún mi lómi mu.’ Kíá ni ó sọ ìkòkò omi rẹ̀ kúrò ní èjìká, tí ó sì wí pé, ‘Omi nìyí, mu, n óo pọn fún àwọn ràkúnmí rẹ pẹlu.’ Mo bá mu omi, ó sì fún àwọn ràkúnmí mi lómi mu pẹlu. Nígbà náà ni mo bi í ọmọ ẹni tí í ṣe. Ó dá mi lóhùn pé, Betueli ọmọ Nahori, tí Milika bí fún un ni baba òun. Nígbà tí mo gbọ́ bẹ́ẹ̀, mo fi òrùka sí imú rẹ̀, mo sì fi ẹ̀gbà ọwọ́ bọ̀ ọ́ lọ́wọ́. Nígbà náà ni mo tẹríba, mo sì sin OLUWA, mo yin OLUWA Ọlọrun Abrahamu, oluwa mi lógo, ẹni tí ó tọ́ mi sí ọ̀nà tààrà láti wá fẹ́ ọmọ ẹbí oluwa mi fún ọmọ rẹ̀. Nítorí náà, ẹ sọ fún mi bí ẹ óo bá ṣe ẹ̀tọ́ pẹlu oluwa mi tabi ẹ kò ní ṣe ẹ̀tọ́, kí n lè mọ̀ bí n óo ṣe rìn.” Labani ati Betueli dáhùn pé, “Ati ọ̀dọ̀ OLUWA ni nǹkan yìí ti wá, àwa kò sì ní sọ pé bẹ́ẹ̀ ni tabi bẹ́ẹ̀ kọ́. Rebeka alára nìyí níwájú rẹ yìí, máa mú un lọ kí ó sì di aya ọmọ oluwa rẹ, bí OLUWA ti wí.” Nígbà tí iranṣẹ Abrahamu gbọ́ ohun tí wọ́n sọ, ó wólẹ̀ ó sì dojúbolẹ̀ níwájú OLUWA. Ó sì mú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye tí a fi fadaka ati wúrà ṣe jáde, ati àwọn aṣọ àtàtà, ó kó wọn fún Rebeka. Ó sì kó àwọn ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye fún arakunrin rẹ̀ ati ìyá rẹ̀ pẹlu. Nígbà náà ni òun ati àwọn tí wọ́n bá a wá tó jẹ, tí wọ́n sì mu, wọ́n sùn níbẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ náà. Bí wọ́n ti jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, iranṣẹ Abrahamu wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí n lọ jíṣẹ́ fún oluwa mi.” Ẹ̀gbọ́n ati ìyá Rebeka dáhùn pé, “Jẹ́ kí omidan náà ṣe bí ọjọ́ mélòó kan sí i lọ́dọ̀ wa, bí kò tilẹ̀ ju ọjọ́ mẹ́wàá lọ, kí ó tó máa bá yín lọ!” Ṣugbọn ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má wulẹ̀ dá mi dúró mọ́, níwọ̀n ìgbà tí OLUWA ti ṣe ọ̀nà mi ní rere, ẹ jẹ́ kí n lọ bá oluwa mi.” Wọ́n dáhùn pé, “Ẹ jẹ́ kí á kúkú pe omidan náà kí á bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀.” Wọ́n bá pe Rebeka, wọ́n bi í pé, “Ṣé o óo máa bá ọkunrin yìí lọ?” Ó dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, n óo lọ.” Wọ́n bá gbà pé kí Rebeka arabinrin wọn máa lọ, pẹlu olùtọ́jú rẹ̀ láti ìgbà èwe rẹ̀, ati iranṣẹ Abrahamu, pẹlu àwọn ọkunrin tí wọ́n bá a wá. Wọ́n súre fún Rebeka, wọ́n wí pé, “Arabinrin wa, o óo bírún, o óo bígba. Àwọn ọmọ rẹ yóo máa borí àwọn ọ̀tá wọn.” Rebeka ati àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ bá gun ràkúnmí, wọ́n tẹ̀lé ọkunrin náà. Bẹ́ẹ̀ ni iranṣẹ náà ṣe mú Rebeka lọ. Kò pẹ́ pupọ lẹ́yìn náà, Isaaki ti wá láti Beeri-lahai-roi, ó sì ń gbé ilẹ̀ Nẹgẹbu. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, ó lọ ṣe àṣàrò ninu pápá, ojú tí ó gbé sókè, ó rí i tí àwọn ràkúnmí ń bọ̀. Ojú tí Rebeka náà gbé sókè, ó rí Isaaki, ó sọ̀kalẹ̀ lórí ràkúnmí. Ó bi iranṣẹ Abrahamu náà pé, “Ta ni ó ń rìn ninu pápá lọ́ọ̀ọ́kán tí ó ń bọ̀ wá pàdé wa yìí?” Iranṣẹ náà dá a lóhùn pé, “Olúwa mi ni.” Rebeka bá mú ìbòjú rẹ̀, ó dà á bojú. Nígbà tí wọ́n pàdé Isaaki, iranṣẹ náà ròyìn gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún un. Isaaki bá mú Rebeka wọ inú àgọ́ Sara ìyá rẹ̀, Rebeka sì di aya rẹ̀, Isaaki sì fẹ́ràn rẹ̀. Nígbà yìí ni Isaaki kò tó ṣọ̀fọ̀ ìyá rẹ̀ mọ́. Abrahamu fẹ́ aya mìíràn, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ketura. Ketura bí Simirani, Jokiṣani, Medani, Midiani, Iṣibaku ati Ṣua fún un. Jokiṣani ni baba Ṣeba ati Dedani. Àwọn ọmọ Dedani ni Aṣurimu, Letuṣimu ati Leumimu. Àwọn ọmọ Midiani ni Efai, Eferi, Hanoku, Abida ati Elidaa. Àwọn ni àwọn ìran tó ṣẹ̀ lọ́dọ̀ Ketura. Ṣugbọn Isaaki ni Abrahamu kó gbogbo ohun ìní rẹ̀ fún. Ẹ̀bùn ni ó fún gbogbo ọmọ tí àwọn obinrin mìíràn bí fún un, kí ó tó kú ni ó sì ti ní kí wọ́n jáde kúrò lọ́dọ̀ Isaaki, kí wọ́n lọ máa gbé ní apá ìlà oòrùn ilẹ̀ náà. Ọdún tí Abrahamu gbé láyé jẹ́ aadọsan-an ọdún ó lé marun-un (175), ó di arúgbó kùjọ́kùjọ́, kí ó tó kú. Àwọn ọmọ rẹ̀, Isaaki ati Iṣimaeli, sin òkú rẹ̀ sinu ihò òkúta Makipela, ninu pápá Efuroni, ọmọ Sohari, ará Hiti, níwájú Mamure. Ilẹ̀ tí Abrahamu rà lọ́wọ́ àwọn ará Hiti ni wọ́n sin ín sí pẹlu Sara aya rẹ̀, Lẹ́yìn ikú Abrahamu, Ọlọrun bukun Isaaki ọmọ rẹ̀. Isaaki sì ń gbé Beeri-lahai-roi. Ìran Iṣimaeli, ọmọ Abrahamu, tí Hagari, ará Ijipti, ọmọ-ọ̀dọ̀ Sara bí fún un nìyí: Àwọn ọmọkunrin Iṣimaeli nìwọ̀nyí bí a ti bí wọn tẹ̀lé ara wọn: Nebaiotu, Kedari, Adibeeli, Mibisamu, Miṣima, Duma, Masa, Hadadi, Tema, Jeturi, Nafiṣi ati Kedema. Àwọn ni ọmọkunrin Iṣimaeli. Wọ́n jẹ́ ọba ẹ̀yà mejila, orúkọ wọn ni wọ́n sì fi ń pe àwọn ìletò ati àgọ́ wọn. Iye ọdún tí Iṣimaeli gbé láyé jẹ́ ọdún mẹtadinlogoje (137). Nígbà tí ó kú a sin ín pẹlu àwọn eniyan rẹ̀. Àwọn ọmọ Iṣimaeli sì ń gbé ilẹ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ láti Hafila títí dé Ṣuri, tí ó wà ní òdìkejì Ijipti, ní apá Asiria. Wọ́n tẹ̀dó sí òdìkejì àwọn eniyan wọn. Ìran Isaaki ọmọ Abrahamu nìyí, Abrahamu ni baba Isaaki. Nígbà tí Isaaki di ẹni ogoji ọdún, ó fẹ́ Rebeka. Rebeka jẹ́ ọmọ Betueli, ará Aramea, tí ń gbé Padani-aramu, ó sì tún jẹ́ arabinrin Labani, ara Aramea. Isaaki gbadura sí OLUWA fún aya rẹ̀ tí ó yàgàn, OLUWA gbọ́ adura rẹ̀, Rebeka aya rẹ̀ sì lóyún. Àwọn ọmọ ń ti ara wọn síhìn-ín sọ́hùn-ún ninu rẹ̀, ó sì wí pé, “Bí ó bá jẹ́ pé báyìí ni yóo máa rí, kí ni mo kúkú wà láàyè fún?” Ó bá lọ wádìí ọ̀rọ̀ náà wò lọ́dọ̀ OLUWA. OLUWA wí fún un pé, “Orílẹ̀-èdè meji ni ó wà ninu rẹ, a óo sì pín àwọn oríṣìí eniyan meji tí o óo bí níyà, ọ̀kan yóo lágbára ju ekeji lọ, èyí ẹ̀gbọ́n ni yóo sì máa sin àbúrò.” Nígbà tí ọjọ́ ìkúnlẹ̀ rẹ̀ pé, ìbejì ni ó bí nítòótọ́. Èyí àkọ́bí pupa, gbogbo ara rẹ̀ dàbí aṣọ onírun. Nítorí náà ni wọ́n fi sọ ọ́ ní Esau. Nígbà tí wọ́n bí èyí ekeji, rírọ̀ ni ó fi ọwọ́ kan rọ̀ mọ́ èyí àkọ́bí ní gìgísẹ̀. Nítorí náà ni wọ́n ṣe sọ ọ́ ní Jakọbu. Ẹni ọgọta ọdún ni Isaaki nígbà tí Rebeka bí wọn. Nígbà tí àwọn ọmọ náà dàgbà, Esau di ògbójú ọdẹ, a sì máa lọ sí oko ọdẹ nígbà gbogbo, ṣugbọn Jakọbu jẹ́ eniyan jẹ́jẹ́, ilé ni ó sì máa ń sábà gbé ní tirẹ̀. Isaaki fẹ́ràn Esau nítorí ẹran ìgbẹ́ tí ó máa ń fún un jẹ nígbà gbogbo, ṣugbọn Jakọbu ni Rebeka fẹ́ràn. Ní ọjọ́ kan, bí Jakọbu ti ń se ẹ̀bẹ lọ́wọ́ ni Esau ti oko ọdẹ dé, ebi sì ti fẹ́rẹ̀ pa á kú. Esau sọ fún Jakọbu pé, “Jọ̀wọ́ fún mi jẹ ninu ẹ̀bẹ tí ó pupa yìí nítorí pé ebi ń pa mí kú lọ.” (Nítorí ọ̀rọ̀ yìí ni wọ́n ṣe ń pè é ní Edomu.) Jakọbu bá dáhùn pé, “Kọ́kọ́ gbé ipò àgbà rẹ fún mi ná.” Esau dá a lóhùn, ó ní, “Ebi ń pa mí kú lọ báyìí, ò ń sọ̀rọ̀ ipò àgbà, kí ni ipò àgbà fẹ́ dà fún mi?” Jakọbu dáhùn pé, “Kọ́kọ́ búra fún mi ná.” Esau bá búra fún Jakọbu, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ gbé ipò àgbà fún un. Jakọbu bá fún Esau ní àkàrà ati ẹ̀bẹ ati ẹ̀fọ́. Nígbà tí Esau jẹ, tí ó mu tán, ó bá tirẹ̀ lọ. Bẹ́ẹ̀ ni Esau ṣe fi ojú tẹmbẹlu ipò àgbà rẹ̀. Ní àkókò kan, ìyàn ńlá kan mú ní ilẹ̀ náà, yàtọ̀ sí ìyàn tí ó mú ní ìgbà Abrahamu. Isaaki bá tọ Abimeleki ọba àwọn ará Filistini lọ ní Gerari. Kí ó tó lọ sí Gerari, Ọlọrun farahàn án, ó sì kìlọ̀ fún un pé kò gbọdọ̀ lọ sí Ijipti, kí ó máa gbé ilẹ̀ tí òun sọ fún un. Ọlọrun ní, “Máa gbé ilẹ̀ yìí, n óo wà pẹlu rẹ, n óo sì bukun ọ, nítorí ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ni n óo fún ní ilẹ̀ wọnyi, n óo sì mú ìlérí mi fún Abrahamu, baba rẹ ṣẹ. N óo sọ àwọn ọmọ rẹ di pupọ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, n óo sì fún wọn ní ilẹ̀ wọnyi. Nípasẹ̀ wọn ni n óo bukun gbogbo orílẹ̀-èdè ayé, nítorí pé Abrahamu gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, ó sì pa gbogbo òfin ati ìlànà mi mọ́ patapata.” Isaaki bá ń gbé Gerari. Nígbà tí àwọn ará ìlú náà bèèrè bí Rebeka ti jẹ́ sí i, ó sọ fún wọn pé arabinrin òun ni. Ẹ̀rù bà á láti jẹ́wọ́ fún wọn pé iyawo òun ni, nítorí ó rò pé àwọn ará ìlú náà lè pa òun nítorí pe Rebeka jẹ́ arẹwà obinrin. Ní ọjọ́ kan, lẹ́yìn tí Isaaki ti ń gbé ìlú náà fún ìgbà pípẹ́, Abimeleki, ọba àwọn ará ìlú Filistia yọjú lójú fèrèsé ààfin rẹ̀, ó rí i tí Isaaki ati Rebeka ń tage. Abimeleki bá pe Isaaki, ó wí pé, “Àṣé iyawo rẹ ni Rebeka! Kí ni ìdí tí o fi pè é ní arabinrin rẹ fún wa?” Isaaki bá dáhùn pé, “Mo rò pé wọ́n lè pa mí nítorí rẹ̀ ni.” Abimeleki bá dá a lóhùn pé, “Irú kí ni o dánwò sí wa yìí? Ǹjẹ́ bí ọ̀kan ninu àwọn eniyan wọnyi bá ti bá aya rẹ lòpọ̀ ńkọ́? O ò bá mú ẹ̀bi wá sórí wa.” Nítorí náà Abimeleki kìlọ̀ fún gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan ọkunrin yìí tabi aya rẹ̀, pípa ni wọn yóo pa á.” Isaaki dá oko ní ilẹ̀ náà, láàrin ọdún kan ṣoṣo ó rí ìkórè ìlọ́po lọ́nà ọgọrun-un (100) ohun tí ó gbìn nítorí OLUWA bukun un. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní àníkún títí ó fi di ọlọ́rọ̀. Ó ní ọpọlọpọ agbo aguntan ati agbo mààlúù, pẹlu ọpọlọpọ iranṣẹ tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ará Filistia bẹ̀rẹ̀ sí jowú rẹ̀. Gbogbo kànga tí àwọn iranṣẹ Abrahamu baba rẹ̀ gbẹ́ ní àkókò tí Abrahamu wà láyé ni àwọn ará Filistia rọ́ yẹ̀ẹ̀pẹ̀ dí. Abimeleki bá wí fún Isaaki pé, “Kúrò lọ́dọ̀ wa, nítorí pé o ti lágbára jù wá lọ.” Isaaki kúrò níbẹ̀, ó lọ tẹ̀dó sí àfonífojì Gerari. Isaaki tún àwọn kànga tí wọ́n ti gbẹ́ nígbà ayé Abrahamu baba rẹ̀ gbẹ́, nítorí pé, kò pẹ́ lẹ́yìn tí Abrahamu kú ni àwọn ará Filistia ti dí wọn. Ó sì sọ àwọn kànga náà ní orúkọ tí baba rẹ̀ sọ wọ́n. Ṣugbọn nígbà tí àwọn iranṣẹ Isaaki gbẹ́ kànga kan ní àfonífojì náà tí wọ́n sì kan omi, àwọn darandaran ará Gerari bá àwọn tí wọn ń da ẹran Isaaki jà, wọ́n wí pé, “Àwa ni a ni omi kànga yìí.” Nítorí náà ni Isaaki ṣe sọ kànga náà ní Eseki, nítorí pé wọ́n bá a jà nítorí rẹ̀. Àwọn iranṣẹ Isaaki tún gbẹ́ kànga mìíràn, òun náà tún dìjà, nítorí náà Isaaki sọ ọ́ ní Sitina. Ó kúrò níbẹ̀, ó lọ gbẹ́ kànga mìíràn, ẹnikẹ́ni kò sì bá a jà sí i, ó bá sọ ọ́ ní Rehoboti, ó wí pé, “Nisinsinyii Ọlọrun ti pèsè ààyè fún wa, a óo sì pọ̀ sí i ní ilẹ̀ yìí.” Láti ibẹ̀ ni ó ti lọ sí Beeriṣeba. OLUWA sì fara hàn án ní òru ọjọ́ tí ó rin ìrìn àjò náà, ó ní, “Èmi ni Ọlọrun Abrahamu, baba rẹ, má bẹ̀rù, nítorí mo wà pẹlu rẹ, n óo bukun ọ, n óo sì sọ àwọn ọmọ rẹ di pupọ nítorí ti Abrahamu iranṣẹ mi.” Ó bá tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀, ó sì sin OLUWA. Níbẹ̀ ni ó pàgọ́ rẹ̀ sí, àwọn iranṣẹ rẹ̀ sì gbẹ́ kànga kan sibẹ. Abimeleki lọ sọ́dọ̀ Isaaki láti Gerari, òun ati Ahusati, olùdámọ̀ràn rẹ̀, ati Fikoli olórí ogun rẹ̀. Isaaki bá bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ tún ń wá lọ́dọ̀ mi, nígbà tí ó jẹ́ pé ẹ kórìíra mi tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ lé mi kúrò lọ́dọ̀ yín?” Wọ́n dáhùn pé, “A rí i dájú pé OLUWA wà pẹlu rẹ, ni a bá rò pé, ó yẹ kí àdéhùn wà láàrin wa, kí á sì bá ọ dá majẹmu, pé o kò ní pa wá lára, gẹ́gẹ́ bí àwa náà kò ti ṣe ọ́ níbi, àfi ire, tí a sì sìn ọ́ kúrò lọ́dọ̀ wa ní alaafia.” Isaaki bá se àsè fún wọn, wọ́n jẹ, wọ́n mu. Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, wọ́n ṣe ìbúra láàrin ara wọn, Isaaki bá sìn wọ́n sọ́nà, wọ́n sì kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ ní alaafia. Ní ọjọ́ náà gan-an ni àwọn iranṣẹ rẹ̀ wá sọ fún un pé àwọn kan omi ninu kànga kan tí àwọn gbẹ́. Ó sọ kànga náà ní Ṣeba. Ìdí nìyí tí orúkọ ìlú náà fi ń jẹ́ Beeriṣeba títí di òní yìí. Nígbà tí Esau di ẹni ogoji ọdún, ó fẹ́ Juditi, ọmọ Beeri, ará Hiti ati Basemati, ọmọ Eloni, ará Hiti. Àwọn obinrin mejeeji yìí han Isaaki ati Rebeka léèmọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ayé sú wọn. Nígbà tí Isaaki di arúgbó, tí ojú rẹ̀ sì di bàìbàì tóbẹ́ẹ̀ tí kò le ríran mọ́, ó pe Esau àkọ́bí rẹ̀, ó ní, “Ọmọ mi.” Esau sì dá a lóhùn pé, “Èmi nìyí.” Isaaki wí pé, “Ṣé o rí i báyìí pé mo ti darúgbó, n kò sì mọ ọjọ́ ikú mi. Kó àwọn ohun ọdẹ rẹ: ọrun ati ọfà rẹ, lọ sí ìgbẹ́, kí o sì pa ẹran wá fún mi. Lẹ́yìn náà, se irú oúnjẹ aládùn tí mo fẹ́ràn fún mi, kí n jẹ ẹ́, kí ọkàn mi lè súre fún ọ kí n tó kú.” Ní gbogbo ìgbà tí Isaaki ń bá Esau ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀, Rebeka ń gbọ́ gbogbo ohun tí wọ́n ń sọ. Nítorí náà nígbà tí Esau jáde lọ sinu ìgbẹ́, Rebeka pe Jakọbu ọmọ rẹ̀, ó sọ fún un, ó ní, “Mo gbọ́ tí baba yín ń bá Esau ẹ̀gbọ́n rẹ sọ̀rọ̀, pé kí ó lọ pa ẹran wá fún òun, kí ó sì se oúnjẹ aládùn kí òun lè jẹ ẹ́, kí òun sì súre fún un níwájú OLUWA kí òun tó kú. Nítorí náà, ọmọ mi, fetí sílẹ̀ kí o sì ṣe ohun tí n óo sọ fún ọ. Lọ sinu agbo ẹran rẹ, kí o sì mú ọmọ ewúrẹ́ meji tí ó lọ́ràá wá, kí n fi se irú oúnjẹ aládùn tí baba yín fẹ́ràn fún un, o óo sì lọ gbé e fún baba yín, kí ó jẹ ẹ́, kí ó baà lè súre fún ọ, kí ó tó kú.” Ṣugbọn Jakọbu dá Rebeka ìyá rẹ̀ lóhùn, ó ní, “Onírun lára ni Esau, ẹ̀gbọ́n mi, n kò sì ní irun lára. Ó ṣeéṣe kí baba mi fi ọwọ́ pa mí lára, yóo wá dàbí ẹni pé mo wá fi ṣe ẹlẹ́yà. Nípa bẹ́ẹ̀ n óo fa ègún sórí ara mi dípò ìre.” Ìyá rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Kí ègún náà wá sí orí mi, ọmọ mi, ṣá gba ohun tí mo wí, kí o sì lọ mú àwọn ewúrẹ́ náà wá.” Jakọbu bá lọ mú wọn wá fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ sì se irú oúnjẹ aládùn tí baba wọn fẹ́ràn. Lẹ́yìn náà Rebeka mú aṣọ Esau, àkọ́bí rẹ̀, tí ó dára jùlọ, tí ó wà nílé lọ́dọ̀ rẹ̀, ó wọ̀ ọ́ fún Jakọbu ọmọ rẹ̀. Ó mú awọ ewúrẹ́ tí ó pa, ó fi bo ọwọ́ Jakọbu ati ibi tí ó ń dán ní ọrùn rẹ̀, ó sì gbé oúnjẹ aládùn tí ó sè ati àkàrà tí ó tọ́jú fún Jakọbu ọmọ rẹ̀. Ni Jakọbu bá tọ baba rẹ̀ lọ, ó pè é, ó ní, “Baba mi,” Baba rẹ̀ bá dá a lóhùn pé, “Èmi nìyí ọmọ mi, ìwọ ta ni?” Jakọbu dá baba rẹ̀ lóhùn, ó ní, “Èmi Esau, àkọ́bí rẹ ni, mo ti ṣe bí o ti wí, dìde jókòó, kí o sì jẹ ninu ẹran ìgbẹ́ tí mo pa, kí o lè súre fún mi.” Ṣugbọn Isaaki bi í léèrè pé, “O ti ṣe é tí o fi rí ẹran pa kíákíá bẹ́ẹ̀ ọmọ mi?” Jakọbu dáhùn pé “OLUWA Ọlọrun rẹ ni ó ṣe ọ̀nà mi ní rere.” Isaaki bá wí tìfura-tìfura pé, “Súnmọ́ mi, kí n fọwọ́ kàn ọ́, kí n lè mọ̀ bóyá Esau ọmọ mi ni ọ́ lóòótọ́.” Jakọbu bá súnmọ́ Isaaki baba rẹ̀, baba rẹ̀ fọwọ́ pa á lára, ó wí pé, “Ọwọ́ Esau ni ọwọ́ yìí, ṣugbọn ohùn Jakọbu ni ohùn yìí.” Kò sì dá Jakọbu mọ̀, nítorí pé ọwọ́ rẹ̀ ní irun bíi ti Esau ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ó bá súre fún un. Ó bèèrè pé, “Ṣé ìwọ gan-an ni Esau, ọmọ mi?” Jakọbu bá dáhùn pé, “Èmi ni.” Nígbà náà ni ó wí pé, “Gbé oúnjẹ náà súnmọ́ mi, kí n jẹ ninu ẹran tí ọmọ mi pa, kí n sì súre fún ọ.” Jakọbu bá gbé oúnjẹ náà súnmọ́ ọn, ó jẹ ẹ́, ó bu ọtí waini fún un, ó sì mu ún. Isaaki baba rẹ̀ bá pè é ó ní, “Súnmọ́ mi, ọmọ mi, kí o sì fi ẹnu kò mí lẹ́nu.” Jakọbu bá súnmọ́ baba rẹ̀, ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu. Baba rẹ̀ gbóòórùn aṣọ rẹ̀, ó sì súre fún un, ó ní, “Òórùn ọmọ mi dàbí òórùn oko tí OLUWA ti bukun. Kí Ọlọrun fún ọ ninu ìrì ọ̀run ati ilẹ̀ tí ó dára ati ọpọlọpọ ọkà ati ọtí waini. Kí àwọn eniyan máa sìn ọ́, kí àwọn orílẹ̀-èdè sì máa tẹríba fún ọ. Ìwọ ni o óo máa ṣe olórí àwọn arakunrin rẹ, àwọn ọmọ ìyá rẹ yóo sì máa tẹríba fún ọ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé ọ, òun ni èpè yóo mọ́, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì súre fún ọ, ìre yóo mọ́ ọn.” Bí Isaaki ti súre fún Jakọbu tán, Jakọbu fẹ́rẹ̀ má tíì jáde kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ tí Esau ẹ̀gbọ́n rẹ̀ fi ti oko ọdẹ dé. Òun náà se oúnjẹ aládùn, ó gbé e tọ baba rẹ̀ wá, ó wí fún un pé, “Baba mi, dìde, kí o jẹ ninu ẹran tí èmi ọmọ rẹ pa, kí o lè súre fún mi.” Isaaki, baba rẹ̀ bi í pé, “Ìwọ ta ni?” Esau bá dá a lóhùn pé, “Èmi ọmọ rẹ ni. Èmi, Esau, àkọ́bí rẹ.” Ara Isaaki bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n gidigidi, ó wí pé, “Ta ló ti kọ́ pa ẹran tí ó gbé e tọ̀ mí wá, tí mo jẹ gbogbo rẹ̀ tán kí o tó dé? Mo sì ti súre fún un. Láìsí àní àní, ìre náà yóo mọ́ ọn.” Nígbà tí Esau gbọ́ ohun tí baba rẹ̀ sọ, ó fi igbe ta, ó sọkún kíkorò, ó wí pé, “Baba mi, súre fún èmi náà.” Ṣugbọn Isaaki dáhùn pé, “Àbúrò rẹ ti wá pẹlu ẹ̀tàn, ó sì ti gba ìre rẹ lọ.” Esau bá dáhùn pé, “Jakọbu ni orúkọ rẹ̀ nítòótọ́. Ó di ìgbà keji tí yóo fi èrú gba ohun tíí ṣe tèmi. Ó ti kọ́kọ́ gba ipò àgbà lọ́wọ́ mi, ó tún wá jí ìre mi gbà lọ.” Esau bá bèèrè lọ́wọ́ baba rẹ̀ pé, “Ṣé o kò wá fi ẹyọ ìre kan pamọ́ fún mi ni?” Isaaki dá a lóhùn, ó ní, “Mo ti fi ṣe olórí rẹ, gbogbo àwọn arakunrin rẹ̀ ni mo sì ti fún un láti fi ṣe iranṣẹ, mo ti fún un ní ọ̀pọ̀ ọkà ati ọtí waini. Kí ló tún wá kù tí mo lè ṣe fún ọ, ọmọ mi?” Esau bẹ̀rẹ̀ sí bẹ baba rẹ̀ pé, “Ṣé ìre kan ṣoṣo ni o ní lẹ́nu ni, baba mi? Áà! Súre fún èmi náà, baba mi.” Esau bá bẹ̀rẹ̀ sí sọkún. Nígbà náà ni Isaaki, baba rẹ̀, dá a lóhùn, ó ní, “Níbi tí ilẹ̀ kò ti lọ́ràá ni o óo máa gbé, níbi tí kò sí ìrì ọ̀run. Pẹlu idà rẹ ni o óo fi wà láàyè, arakunrin rẹ ni o óo sì máa sìn, ṣugbọn nígbà tí ó bá yá, o óo já ara rẹ gbà, o óo sì bọ́ àjàgà rẹ̀ kúrò lọ́rùn rẹ.” Nítorí irú ìre tí baba wọn sú fún Esau yìí ni Esau ṣe kórìíra Jakọbu. Esau dá ara rẹ̀ lọ́kàn le ó ní, “Ìgbà mélòó ni ó kù tí baba wa yóo fi kú? Bí ó bá ti kú ni n óo pa Jakọbu, arakunrin mi.” Ṣugbọn wọ́n sọ ohun tí Esau, àkọ́bí Rebeka ń wí fún Rebeka ìyá rẹ̀. Rebeka bá ranṣẹ pe Jakọbu, ó wí fún un pé, “O jẹ́ mọ̀, Esau ẹ̀gbọ́n rẹ ń dá ara rẹ̀ lọ́kàn le pẹlu ìpinnu láti pa ọ́. Nítorí náà, ọmọ mi, gbọ́ ohun tí n óo sọ fún ọ yìí, wá gbéra kí o sálọ bá Labani, arakunrin mi, ní Harani. Kí o sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ títí tí inú tí ń bí arakunrin rẹ yóo fi rọ̀, tí inú rẹ̀ yóo yọ́, tí yóo sì gbàgbé ohun tí o ti ṣe sí i, n óo wá ranṣẹ pè ọ́ pada nígbà náà. Mo ha gbọdọ̀ ṣọ̀fọ̀ ẹ̀yin mejeeji lọ́jọ́ kan náà bí?” Rebeka sọ fún Isaaki, ó ní, “Ọ̀rọ̀ àwọn obinrin Hiti wọnyi mú kí ayé sú mi. Bí Jakọbu bá lọ fẹ́ ọ̀kan ninu àwọn obinrin ará Hiti, irú àwọn obinrin ilẹ̀ yìí, irú ire wo ni ó tún kù fún mi láyé mọ́?” Isaaki bá pe Jakọbu, ó súre fún un, ó sì pàṣẹ fún un pé kò gbọdọ̀ fẹ́ ninu àwọn ọmọbinrin ará Kenaani. Ó ní, “Dìde, lọ sí ilé Betueli, baba ìyá rẹ, ní Padani-aramu, kí o sì fẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Labani, arakunrin ìyá rẹ. Ọlọrun Olodumare yóo bukun ọ, yóo fún ọ ní ọmọ pupọ, yóo sì sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá. Ìre tí ó sú fún Abrahamu yóo mọ́ ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ lórí. Ilẹ̀ tí ó fún Abrahamu, níbi tí Abrahamu ti jẹ́ àjèjì yóo sì di tìrẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni Isaaki ṣe rán Jakọbu jáde lọ sí Padani-aramu lọ́dọ̀ Labani, ọmọ Betueli, ará Aramea, arakunrin Rebeka, ìyá Jakọbu ati Esau. Esau rí i pé Isaaki ti súre fún Jakọbu, ó sì ti rán an lọ sí Padani-aramu kí ó lọ fẹ́ iyawo, ati pé nígbà tí ó ń súre fún un, ó pàṣẹ fún un pé kò gbọdọ̀ fẹ́ ninu àwọn ọmọbinrin ará Kenaani. Ó sì tún rí i pé Jakọbu gbọ́ ti baba ati ìyá rẹ̀, ó lọ sí Padani-aramu bí wọ́n ti sọ, ati pé inú Isaaki, baba wọn kò dùn sí i pé kí wọn fẹ́ ọmọ ilẹ̀ Kenaani níyàwó. Nítorí náà Esau lọ sọ́dọ̀ Iṣimaeli ọmọ Abrahamu, ó sì fẹ́ Mahalati ọmọ rẹ̀, tíí ṣe arabinrin Nebaiotu, ó fi kún àwọn aya tí ó ti ní. Jakọbu kúrò ní Beeriṣeba, ó ń lọ sí Harani. Nígbà tí ó dé ibìkan tí ó rí i pé ilẹ̀ ti ń ṣú, ó gbé ọ̀kan ninu àwọn òkúta tí ó wà níbẹ̀, ó fi ṣe ìrọ̀rí, ó sì sùn. Nígbà tí ó sùn, ó lá àlá kan, ó rí àkàsọ̀ kan lójú àlá, wọ́n gbé e kalẹ̀, orí rẹ̀ kan ojú ọ̀run. Ó wá rí i tí àwọn angẹli Ọlọrun ń gùn ún lọ sókè sódò. OLUWA pàápàá dúró lókè rẹ̀, ó wí fún un pé, “Èmi ni OLUWA Ọlọrun Abrahamu baba rẹ ati Ọlọrun Isaaki, ilẹ̀ tí o dùbúlẹ̀ sí yìí, ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ni n óo fi fún. Àwọn ọmọ rẹ yóo pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, o óo sì gbilẹ̀ káàkiri sí ìhà ìwọ̀ oòrùn ati sí ìhà ìlà oòrùn, sí ìhà àríwá ati sí ìhà gúsù nípasẹ̀ rẹ ati àwọn ọmọ rẹ ni n óo bukun aráyé. Wò ó, mo wà pẹlu rẹ, n óo pa ọ́ mọ́ níbikíbi tí o bá lọ, n óo sì mú ọ pada wá sí ilẹ̀ yìí, nítorí pé n kò ní fi ọ́ sílẹ̀ títí tí n óo fi ṣe gbogbo ohun tí mo sọ fún ọ.” Nígbà tí Jakọbu tají ní ojú oorun rẹ̀, ó ní, “Dájúdájú OLUWA ń bẹ níhìn-ín, n kò sì mọ̀!” Ẹ̀rù bà á, ó sì wí pé, “Ààrin yìí mà tilẹ̀ bani lẹ́rù pupọ o! Ibí yìí kò lè jẹ́ ibòmíràn bíkòṣe ilé Ọlọrun, ibí gan-an ni ẹnu ibodè ọ̀run.” Jakọbu bá dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, ó gbé òkúta tí ó fi ṣe ìrọ̀rí nàró gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ̀n, ó sì da òróró sórí rẹ̀. Ó sọ ibẹ̀ ní Bẹtẹli, ṣugbọn Lusi ni orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀ rí. Jakọbu bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan, ó ní “Bí Ọlọrun bá wà pẹlu mi, bí ó bá sì pa mí mọ́ ní ọ̀nà ibi tí mò ń lọ yìí, tí ó bá fún mi ní oúnjẹ jẹ, tí ó sì fún mi ni aṣọ wọ̀, tí mo bá sì pada dé ilé baba mi ní alaafia, OLUWA ni yóo máa jẹ́ Ọlọrun mi. Òkúta tí mo sì gbé nàró bí ọ̀wọ̀n yìí yóo di ilé Ọlọrun, n óo sì fún ìwọ Ọlọrun ní ìdámẹ́wàá ohun gbogbo tí o bá fún mi.” Jakọbu tún ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ, nígbà tí ó ṣe, ó dé ilẹ̀ àwọn ará ìlà oòrùn. Bí ó ti gbójú sókè, ó rí kànga kan ninu pápá, ati agbo aguntan mẹta tí wọ́n dùbúlẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, nítorí pé láti inú kànga yìí ni wọ́n ti ń fún àwọn aguntan náà ní omi mu. Òkúta tí wọ́n sì yí dí ẹnu kànga náà tóbi pupọ. Nígbà tí gbogbo àwọn olùṣọ́-aguntan bá da aguntan wọn dé ìdí kànga yìí ni wọ́n tó ń yí òkúta náà kúrò lẹ́nu kànga. Lẹ́yìn náà, wọn á fún àwọn aguntan wọ́n lómi mu, wọ́n á sì yí òkúta náà pada sẹ́nu kànga. Jakọbu bá bi wọ́n léèrè pé, “Ẹ̀yin arakunrin mi, níbo ni ẹ ti wá?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Harani ni.” Ó tún bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ Labani ọmọ Nahori?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “A mọ̀ ọ́n.” Ó tún bi wọ́n pé, “Ṣé alaafia ni ó wà?” Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Alaafia ni, wò ó, Rakẹli, ọmọbinrin rẹ̀, ni ó ń da aguntan bọ̀ ní ọ̀kánkán yìí.” Jakọbu sọ pé, “Oòrùn ṣì wà lókè, kò tíì tó àkókò láti kó àwọn ẹran jọ sójú kan, ẹ tètè fún àwọn aguntan ní omi mu, kí ẹ sì dà wọ́n pada lọ jẹ koríko sí i.” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Kò ṣeéṣe, àfi bí gbogbo àwọn olùṣọ́-aguntan bá dé tán, tí a bá yí òkúta kúrò lórí kànga, nígbà náà ni a tó lè fún àwọn aguntan ní omi mu.” Bí ó ti ń bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni Rakẹli dé pẹlu agbo aguntan baba rẹ̀, nítorí pé òun ni ó ń tọ́jú wọn. Nígbà tí Jakọbu rí Rakẹli, ọmọ Labani, tíí ṣe arakunrin ìyá rẹ̀, ati agbo aguntan Labani, ó yí òkúta náà kúrò lẹ́nu kànga, ó sì pọn omi fún wọn. Jakọbu bá fi ẹnu ko Rakẹli lẹ́nu, ó sì bú sẹ́kún. Ó sọ fún Rakẹli pé, ìbátan baba rẹ̀ ni òun jẹ́, ati pé ọmọ Rebeka ni òun. Rakẹli bá sáré lọ sọ fún baba rẹ̀. Nígbà tí Labani gbọ́ ìròyìn ayọ̀ náà pé, Jakọbu ọmọ arabinrin òun dé, ó sáré lọ pàdé rẹ̀, ó dì mọ́ ọn, ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu, ó sì mú un wá sí ilé. Jakọbu ròyìn ohun gbogbo tí ó ti ṣẹlẹ̀ fún Labani. Labani bá dá a lọ́kàn le, ó ní, “Láìsí àní àní, ẹ̀jẹ̀ kan náà ni wá” Jakọbu sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ fún oṣù kan. Lẹ́yìn náà Labani sọ fún un pé, “O wá gbọdọ̀ máa sìn mí lásán nítorí pé o jẹ́ ìbátan mi? Sọ fún mi, èló ni o fẹ́ máa gbà?” Labani ní ọmọbinrin meji, èyí ẹ̀gbọ́n ń jẹ́ Lea, èyí àbúrò sì ń jẹ́ Rakẹli. Ojú Lea kò fi bẹ́ẹ̀ fanimọ́ra, ṣugbọn Rakẹli jẹ́ arẹwà, ojú rẹ̀ sì fanimọ́ra. Jakọbu nífẹ̀ẹ́ Rakẹli, nítorí náà, ó sọ fún Labani pé, “N óo sìn ọ́ ní ọdún meje nítorí Rakẹli, ọmọ rẹ kékeré.” Labani bá dá a lóhùn pé, “Ó tẹ́ mi lọ́rùn láti fún ọ ju kí n fún ẹni ẹlẹ́ni lọ. Máa bá mi ṣiṣẹ́.” Jakọbu bá sin Labani fún ọdún meje nítorí Rakẹli, ó sì dàbí ọjọ́ mélòó kan lójú rẹ̀ nítorí ìfẹ́ tí ó ní sí Rakẹli. Nígbà tí ó yá, Jakọbu sọ fún Labani pé, “Fún mi ní aya mi, kí á lè ṣe igbeyawo, nítorí ọjọ́ ti pé.” Labani bá pe gbogbo àwọn ọkunrin ibẹ̀ jọ, ó se àsè ńlá fún wọn. Ṣugbọn nígbà tí ó di àṣáálẹ́, Lea ni wọ́n mú wá fún Jakọbu dípò Rakẹli, Jakọbu sì bá a lòpọ̀. Labani fi Silipa ẹrubinrin rẹ̀ fún Lea pé kí ó máa ṣe iranṣẹ fún un. Nígbà tí ó di òwúrọ̀, Jakọbu rí i pé Lea ni wọ́n mú wá fún òun. Ó bi Labani, ó ní, “Irú kí ni o ṣe sí mi yìí? Ṣebí nítorí Rakẹli ni mo fi sìn ọ́? Èéṣe tí o tàn mí jẹ?” Labani dáhùn, ó ní, “Ní ilẹ̀ tiwa níhìn-ín, àwa kì í fi àbúrò fọ́kọ ṣáájú ẹ̀gbọ́n. Fara balẹ̀ parí àwọn ètò ọ̀sẹ̀ igbeyawo ti eléyìí, n óo sì fún ọ ní ekeji náà, ṣugbọn o óo tún sìn mí ní ọdún meje sí i.” Jakọbu gbà bẹ́ẹ̀, ó ṣe ọ̀sẹ̀ igbeyawo Lea parí, lẹ́yìn náà Labani fa Rakẹli, ọmọ rẹ̀ fún un. Labani fi Biliha, ẹrubinrin rẹ̀ fún Rakẹli, ọmọbinrin rẹ̀, pé kí ó máa ṣe iranṣẹ fún un. Jakọbu bá Rakẹli náà lòpọ̀, ó sì fẹ́ràn rẹ̀ ju Lea lọ, ó sì sin Labani fún ọdún meje sí i. Nígbà tí OLUWA rí i pé Jakọbu kò fẹ́ràn Lea, ó fún Lea ní ọmọ bí, ṣugbọn Rakẹli yàgàn. Lea lóyún, ó bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọ́ ní Reubẹni, ó ní, “Nítorí OLUWA ti ṣíjú wo ìpọ́njú mi; nisinsinyii, ọkọ mi yóo fẹ́ràn mi.” Ó tún lóyún, ó tún bí ọkunrin, ó ní, “Nítorí pé OLUWA ti gbọ́ pé wọ́n kórìíra mi ni ó ṣe fún mi ní ọmọ yìí pẹlu.” Ó bá sọ ọ́ ní Simeoni. Ó tún lóyún, ó sì tún bí ọkunrin, ó ní, “Ọkọ mi gbọdọ̀ faramọ́ mi wàyí, nítorí pé ó di ọkunrin mẹta tí mo bí fún un”, nítorí náà, ó sọ ọmọ náà ní Lefi. Ó tún lóyún ó sì tún bí ọkunrin, ó ní, “Wàyí o, n óo yin OLUWA,” ó bá sọ ọ́ ní Juda. Lẹ́yìn rẹ̀, kò bímọ mọ́. Nígbà tí Rakẹli rí i pé òun kò bímọ fún Jakọbu rárá, ó bẹ̀rẹ̀ sí jowú ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ó wí fún Jakọbu pé, “Tí o kò bá fẹ́ kí n kú sí ọ lọ́rùn, fún mi lọ́mọ.” Inú bí Jakọbu pupọ sí ọ̀rọ̀ tí Rakẹli sọ, ó dá a lóhùn pé, “Ṣé èmi ni Ọlọrun tí kò fún ọ lọ́mọ ni?” Rakẹli bá dáhùn, ó ní, “Biliha, iranṣẹbinrin mi nìyí, bá a lòpọ̀, kí ó bímọ sí mi lọ́wọ́, kí èmi náà sì lè ti ipa rẹ̀ di ọlọ́mọ.” Ó bá fún Jakọbu ní Biliha, iranṣẹbinrin rẹ̀ kí ó fi ṣe aya, Jakọbu sì bá a lòpọ̀. Biliha lóyún, ó bí ọmọkunrin kan fún Jakọbu. Rakẹli bá sọ pé, “Ọlọrun dá mi láre, ó gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi, ó sì fún mi ní ọmọkunrin kan.” Nítorí náà, ó sọ ọmọ náà ní Dani. Biliha, iranṣẹbinrin Rakẹli tún lóyún, ó bí ọmọkunrin keji fún Jakọbu. Rakẹli bá sọ pé, “Ìjàkadì gidi ni mo bá ẹ̀gbọ́n mi jà, mo sì ṣẹgun,” ó sì sọ ọmọ náà ní Nafutali. Nígbà tí Lea rí i pé òun kò bímọ mọ́, ó fún Jakọbu ní Silipa, iranṣẹbinrin rẹ̀, kí ó fi ṣe aya. Iranṣẹbinrin Lea bí ọmọkunrin kan fún Jakọbu. Lea bá sọ pé, “Oríire.” Ó bá sọ ọmọ náà ní Gadi. Iranṣẹbinrin Lea tún bí ọmọkunrin mìíràn fún Jakọbu. Lea bá ní, “Mo láyọ̀, nítorí pé àwọn obinrin yóo máa pè mí ní Ẹni-Ayọ̀,” nítorí náà ó sọ ọmọ náà ní Aṣeri. Ní àkókò ìkórè ọkà alikama, Reubẹni bá wọn lọ sí oko, ó sì já èso mandiraki bọ̀ fún Lea ìyá rẹ̀. Nígbà tí Rakẹli rí i, ó bẹ Lea pé kí ó fún òun ninu èso mandiraki ọmọ rẹ̀. Ṣugbọn Lea dá a lóhùn pé, “O gba ọkọ mọ́ mi lọ́wọ́, kò tó ọ, o tún fẹ́ gba èso mandiraki ọmọ mi lọ́wọ́ mi?” Rakẹli bá dá a lóhùn, ó ní: “Bí o bá fún mi ninu èso mandiraki ọmọ rẹ, ọ̀dọ̀ rẹ ni Jakọbu yóo sùn lálẹ́ òní.” Ní ìrọ̀lẹ́, nígbà tí Jakọbu ti oko dé, Lea jáde lọ pàdé rẹ̀, ó sọ fún un pé, “Ọ̀dọ̀ mi ni o gbọdọ̀ sùn ní alẹ́ òní, èso mandiraki ọmọ mi ni mo fi san owó ọ̀yà rẹ. Jakọbu bá sùn lọ́dọ̀ rẹ̀ di ọjọ́ keji.” Ọlọrun gbọ́ ẹ̀bẹ̀ Lea, ó lóyún, ó bí ọmọkunrin karun-un. Lea ní “Ọlọrun san ẹ̀san fún mi, nítorí pé mo fún ọkọ mi ní iranṣẹbinrin mi.” Ó bá sọ ọmọ náà ní Isakari. Lea tún lóyún, ó bí ọkunrin kẹfa. Ó ní, “Ọlọrun ti fi ẹ̀bùn rere fún mi, nígbà yìí ni ọkọ mi yóo tó bu ọlá fún mi, nítorí pé mo bí ọkunrin mẹfa fún un,” nítorí náà ó sọ ọmọ náà ní Sebuluni. Lẹ́yìn náà, ó bí obinrin kan, ó sọ ọ́ ní Dina. Lẹ́yìn náà ni Ọlọrun ranti Rakẹli, ó gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀, ó sì ṣí inú rẹ̀. Rakẹli lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan. Ó wí pé, “Ọlọrun ti mú ẹ̀gàn mi kúrò,” ó sọ ọmọ náà ní Josẹfu; ó ní, “Kí OLUWA má ṣàì fún mi ní ọmọkunrin mìíràn.” Lẹ́yìn tí Rakẹli bí Josẹfu, Jakọbu tọ Labani lọ, ó bẹ̀ ẹ́ pé “Jẹ́ kí n pada sí ilé mi. Jẹ́ kí àwọn aya ati àwọn ọmọ mi máa bá mi lọ, nítorí wọn ni mo ṣe sìn ọ́. Jẹ́ kí n máa lọ, ìwọ náà ṣá mọ̀ bí mo ti sìn ọ́ tó.” Ṣugbọn Labani dá a lóhùn pé, “Gbà mí láàyè kí n sọ ọ̀rọ̀ yìí, mo ti ṣe àyẹ̀wò, mo sì ti rí i pé nítorí tìrẹ ni OLUWA ṣe bukun mi, sọ iye tí o bá fẹ́ máa gbà, n óo sì máa san án fún ọ.” Jakọbu bá dáhùn pé, “Ìwọ náà mọ̀ bí mo ti sìn ọ́ ati bí àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ ti ṣe dáradára lọ́wọ́ mi. Ẹran ọ̀sìn díẹ̀ ni o ní kí n tó dé ọ̀dọ̀ rẹ, díẹ̀ náà ti di pupọ nisinsinyii OLUWA ti bukun ọ ní gbogbo ọ̀nà nítorí tèmi. Nígbà wo ni èmi gan-an yóo tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àkójọ àwọn ohun tí mo lè pè ní tèmi?” Labani bá bi í léèrè pé, “Kí ni kí n máa fún ọ?” Jakọbu dáhùn pé, “Má fún mi ní ohunkohun, bí o bá gbà láti ṣe ohun kan fún mi, n óo tún máa bá ọ tọ́jú àwọn agbo ẹran rẹ. Jẹ́ kí n bọ́ sí ààrin àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ lónìí, kí n sì ṣa gbogbo ọmọ aguntan dúdú, ati gbogbo ọmọ ewúrẹ́ ati aguntan tí ó ní dúdú tóótòòtóó lára, tí ó dàbí adíkálà, irú àwọn ẹran wọnyi ni n óo máa gbà fún iṣẹ́ tí mò ń ṣe fún ọ. Bẹ́ẹ̀ ni òdodo mi yóo jẹ́rìí gbè mí ní ọjọ́ iwájú, nígbà tí o bá wá wo ọ̀yà mi. Èyíkéyìí tí kò bá jẹ́ dúdú ninu àwọn aguntan, tabi ewúrẹ́ tí àwọ̀ rẹ̀ kò bá ní dúdú tóótòòtóó tí o bá rí láàrin àwọn ẹran mi, a jẹ́ pé mo jí i gbé ni.” Labani bá dá a lóhùn pé, “Ó dára, ohun tí o wí gan-an ni a óo ṣe.” Ṣugbọn ní ọjọ́ náà gan-an ni Labani ṣa gbogbo ewúrẹ́ ati òbúkọ tí àwọ̀ wọn ní funfun tóótòòtóó, tabi tí ó dàbí adíkálà, ati gbogbo àwọn tí wọ́n ní funfun lára, ati gbogbo àwọn aguntan dúdú, ó kó wọn lé àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́. Òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ bá kó wọn lọ jìnnà sí Jakọbu, ní ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ mẹta. Jakọbu bá ń tọ́jú agbo ẹran Labani tí ó kù. Jakọbu gé ọ̀pá igi populari ati ti alimọndi, ati ti pilani tútù, ó bó àwọn ọ̀pá náà ní àbófín, ó jẹ́ kí funfun wọn hàn síta. Ó to àwọn ọ̀pá wọnyi siwaju àwọn ẹran níbi tí wọ́n ti ń mu omi, nítorí pé, nígbà tí wọ́n bá wá mu omi ni wọ́n máa ń gùn. Àwọn ẹran náà ń gun ara wọn níwájú àwọn ọ̀pá wọnyi, wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bí ọmọ tí àwọ̀ wọn dàbí adíkálà ati àwọn tí wọ́n ní funfun tóótòòtóó. Jakọbu ṣa àwọn ọmọ aguntan wọnyi sọ́tọ̀, ó sì tún mú kí gbogbo agbo ẹran Labani dojú kọ àwọn ẹran tí àwọ̀ wọn ní funfun tóótòòtóó tabi tí ó dàbí adíkálà, tabi àwọn tí wọ́n jẹ́ dúdú, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣa àwọn ẹran tirẹ̀ sinu agbo kan lọ́tọ̀, kò pa wọ́n pọ̀ pẹlu ti Labani. Nígbà tí àwọn ẹran tí ara wọ́n le dáradára láàrin agbo bá ń gùn, Jakọbu a fi àwọn ọ̀pá náà siwaju wọn, kí wọ́n lè máa gùn láàrin wọn. Ṣugbọn nígbà tí àwọn ẹran tí kò lókun ninu tóbẹ́ẹ̀ bá ń gùn, kì í fi àwọn ọ̀pá náà siwaju wọn, báyìí ni àwọn ẹran tí kò lókun ninu di ti Labani, àwọn tí wọ́n lókun ninu sì di ti Jakọbu. Bẹ́ẹ̀ ni Jakọbu ṣe di ọlọ́rọ̀ gidigidi, ó sì ní àwọn agbo ẹran ńláńlá, ọpọlọpọ iranṣẹbinrin ati iranṣẹkunrin, ràkúnmí ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Jakọbu gbọ́ pé àwọn ọmọ Labani ń sọ pé òun ti gba gbogbo ohun tíí ṣe ti baba wọn, ninu ohun ìní baba wọn ni òun sì ti kó gbogbo ọrọ̀ òun jọ. Jakọbu pàápàá kíyèsí i pé Labani kò fi ojurere wo òun mọ́ bíi ti àtẹ̀yìnwá. Nígbà náà ni OLUWA sọ fún Jakọbu pé, “Pada lọ sí ilẹ̀ baba rẹ ati ti àwọn ìbátan rẹ, n óo sì wà pẹlu rẹ.” Jakọbu bá ranṣẹ pe Rakẹli ati Lea sinu pápá níbi tí agbo ẹran rẹ̀ wà. Ó wí fún wọn pé, “Mo ṣàkíyèsí pé baba yín kò fi ojurere wò mí bíi ti àtẹ̀yìnwá mọ́, ṣugbọn Ọlọrun baba mi wà pẹlu mi. Ẹ̀yin náà mọ̀ pé gbogbo agbára mi ni mo ti fi sin baba yín, sibẹ, baba yín rẹ́ mi jẹ, ó sì yí owó ọ̀yà mi pada nígbà mẹ́wàá, ṣugbọn Ọlọrun kò gbà fún un láti pa mí lára. Bí ó bá wí pé àwọn ẹran tí ó ní funfun tóótòòtóó ni yóo jẹ́ owó ọ̀yà mi, gbogbo ẹran inú agbo a sì bí onífunfun tóótòòtóó. Bí ó bá sì wí pé, àwọn ẹran tí ó bá ní àwọ̀ tí ó dàbí adíkálà ni yóo jẹ́ tèmi, gbogbo ẹran inú agbo a sì bí ọmọ tí àwọ̀ wọn dàbí adíkálà. Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun ṣe gba gbogbo ẹran baba yín tí ó sì fi wọ́n fún mi. “Ní àkókò tí àwọn ẹran náà ń gùn, mo rí i lójú àlá pé àwọn òbúkọ tí wọn ń gun àwọn ẹran jẹ́ àwọn tí àwọ̀ wọn dàbí ti adíkálà ati àwọn onífunfun tóótòòtóó ati àwọn abilà. Angẹli Ọlọrun bá sọ fún mi ní ojú àlá náà, ó ní, ‘Jakọbu.’ Mo dáhùn pé, ‘Èmi nìyí.’ Angẹli Ọlọrun bá sọ pé, ‘Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wò ó pé gbogbo àwọn òbúkọ tí ó ń gun àwọn ẹran inú agbo jẹ́ aláwọ̀ adíkálà ati onífunfun tóótòòtóó ati abilà, nítorí mo ti rí gbogbo ohun tí Labani ń ṣe sí ọ. Èmi ni Ọlọrun Bẹtẹli, níbi tí o ti ta òróró sórí òkúta tí o sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún mi. Dìde nisinsinyii, kí o jáde kúrò ní ilẹ̀ yìí, kí o sì pada sí ilẹ̀ tí wọ́n gbé bí ọ.’ ” Ni Rakẹli ati Lea bá dá a lóhùn pé, “Ǹjẹ́ ogún kan tilẹ̀ tún kù fún wa ní ilé baba wa mọ́? Ǹjẹ́ kò ti kà wá kún àjèjì? Nítorí pé ó ti tà wá, ó sì ti ná owó tí ó gbà lórí wa tán. Ti àwa ati àwọn ọmọ wa ni ohun ìní gbogbo tí Ọlọrun gbà lọ́wọ́ baba wa jẹ́, nítorí náà, gbogbo ohun tí Ọlọrun bá sọ fún ọ láti ṣe, ṣe é.” Jakọbu bá dìde, ó gbé àwọn ọmọ ati àwọn aya rẹ̀ gun ràkúnmí. Ó bẹ̀rẹ̀ sí da gbogbo àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀ tí ó ti kó jọ ní Padani-aramu siwaju, ó ń pada lọ sọ́dọ̀ Isaaki baba rẹ̀ ní ilẹ̀ Kenaani. Ní àkókò yìí, Labani wà níbi tí ó ti ń gé irun àwọn aguntan rẹ̀, Rakẹli bá jí àwọn ère oriṣa ilé baba rẹ̀ kó. Ọgbọ́n ni Jakọbu lò fún Labani ará Aramea, nítorí pé Jakọbu kò sọ fún un pé òun fẹ́ sálọ. Ó dìde, ó kó gbogbo ohun tí ó ní, ó sá gòkè odò Yufurate, ó doríkọ ọ̀nà agbègbè olókè Gileadi. Ní ọjọ́ kẹta, nígbà tí wọ́n sọ fún Labani pé Jakọbu ti sálọ, ó kó àwọn ìbátan rẹ̀, ó sì tọpa rẹ̀ fún ọjọ́ meje, ó bá a ní agbègbè olókè Gileadi. Ṣugbọn Ọlọrun sọ fún Labani ará Aramea lóru lójú àlá, ó ní, “Ṣọ́ra, má bá Jakọbu sọ ohunkohun, kì báà jẹ́ rere tabi buburu.” Labani lé Jakọbu bá níbi tí ó pàgọ́ rẹ̀ sí ní orí òkè náà, Labani ati àwọn ìbátan rẹ̀ sì pàgọ́ tiwọn sí agbègbè olókè Gileadi. Labani pe Jakọbu, ó ní, “Èéṣe tí o fi ṣe báyìí? O tàn mí jẹ, o sì kó àwọn ọmọbinrin mi sá bí ẹrú tí wọ́n kó lójú ogun. Èéṣe tí o fi tàn mí jẹ, tí o yọ́ lọ láìsọ fún mi? Ṣebí ǹ bá fi ayọ̀, ati orin ati ìlù ati hapu sìn ọ́. Èéṣe tí o kò fún mi ní anfaani láti fi ẹnu ko àwọn ọmọ mi lẹ́nu kí n fi dágbére fún wọn? Ìwà òmùgọ̀ ni o hù yìí. Mo ní agbára láti ṣe ọ́ níbi, ṣugbọn Ọlọrun baba rẹ bá mi sọ̀rọ̀ ní òru àná pé kí n ṣọ́ra, kí n má bá ọ sọ ohunkohun, kì báà jẹ́ rere tabi buburu. Mo mọ̀ pé ọkàn rẹ fà sí ilé ni o fi sá, ṣugbọn, èéṣe tí o fi jí àwọn ère oriṣa mi kó?” Jakọbu bá dá Labani lóhùn, ó ní, “Ẹ̀rù ni ó bà mí, mo rò pé o óo fi ipá gba àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ mi. Ní ti àwọn ère oriṣa rẹ, bí o bá bá a lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, pípa ni a óo pa olúwarẹ̀. Níwájú gbogbo ìbátan wa, tọ́ka sí ohunkohun tí ó bá jẹ́ tìrẹ ninu gbogbo ohun tí ó wà lọ́dọ̀ mi, kí o sì mú un.” Jakọbu kò mọ̀ rárá pé Rakẹli ni ó jí àwọn ère oriṣa Labani kó. Labani bá wá inú àgọ́ Jakọbu, ati ti Lea ati ti àwọn iranṣẹbinrin mejeeji, ṣugbọn kò rí àwọn ère oriṣa rẹ̀. Bí ó ti jáde ninu àgọ́ Lea ni ó lọ sí ti Rakẹli. Rakẹli ni ó kó àwọn ère oriṣa náà, ó dì wọ́n sinu àpò gàárì ràkúnmí, ó sì jókòó lé e mọ́lẹ̀. Labani tú gbogbo inú àgọ́ rẹ̀, ṣugbọn kò rí wọn. Rakẹli wí fún baba rẹ̀ pé, “Jọ̀wọ́, oluwa mi, má bínú pé n kò dìde lójú kan tí mo jókòó sí, mò ń ṣe nǹkan oṣù mi lọ́wọ́ ni.” Bẹ́ẹ̀ ni Labani ṣe wá àwọn ère oriṣa rẹ̀ títí, ṣugbọn kò rí wọn. Inú wá bí Jakọbu, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sí Labani, ó ní, “Kí ni mo ṣe? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ tí o fi ń tọpa mi kíkankíkan bẹ́ẹ̀? Nígbà tí o tú gbogbo ẹrù mi palẹ̀, àwọn nǹkan rẹ wo ni o rí níbẹ̀? Kó o kalẹ̀ níwájú àwọn ìbátan mi ati àwọn ìbátan rẹ, kí wọ́n lè dájọ́ láàrin wa. Fún ogún ọdún tí mo fi bá ọ gbé, ewúrẹ́ rẹ kan tabi aguntan kan kò sọnù rí, bẹ́ẹ̀ ni n kò jí àgbò rẹ kan pajẹ rí. Èyí tí ẹranko burúkú bá pajẹ tí n kò bá gbé òkú rẹ̀ wá fún ọ, èmi ni mò ń fara mọ́ ọn. O máa ń gba ààrọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ mi, ìbáà jẹ́ ní òru ni ó sọnù tabi ní ọ̀sán. Bẹ́ẹ̀ ni mò ń wà ninu oòrùn lọ́sàn-án ati ninu òtútù lóru, oorun kò sì sí lójú mi. Ó di ogún ọdún tí mo ti dé ọ̀dọ̀ rẹ, mo fi ọdún mẹrinla sìn ọ́ nítorí àwọn ọmọbinrin rẹ, ati ọdún mẹfa fún agbo ẹran rẹ. Ìgbà mẹ́wàá ni o sì pa owó ọ̀yà mi dà. Bí kò bá jẹ́ pé Ọlọrun baba mi wà pẹlu mi, àní, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun tí Isaaki ń sìn tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù, láìsí àní àní, ìwọ ìbá ti lé mi lọ lọ́wọ́ òfo kó tó di àkókò yìí. Ọlọrun rí ìyà mi ati iṣẹ́ ọwọ́ mi ni ó fi kìlọ̀ fún ọ ní alẹ́ àná.” Labani bá dá Jakọbu lóhùn, ó ní, “Èmi ni mo ni àwọn ọmọbinrin wọnyi, tèmi sì ni àwọn ọmọ wọnyi pẹlu, èmi náà ni mo ni àwọn agbo ẹran, àní gbogbo ohun tí ò ń wò wọnyi, èmi tí mo ni wọ́n nìyí. Ṣugbọn kí ni mo lè ṣe lónìí sí àwọn ọmọbinrin mi wọnyi ati sí àwọn ọmọ tí wọ́n bí? Ó dára, jẹ́ kí èmi pẹlu rẹ dá majẹmu, kí majẹmu náà sì jẹ́ ẹ̀rí láàrin àwa mejeeji.” Jakọbu bá gbé òkúta kan, ó fi sọlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ̀n. Ó sì sọ fún àwọn ìbátan rẹ̀ kí wọ́n kó òkúta jọ. Wọ́n sì kó òkúta jọ, wọ́n fi ṣe òkítì ńlá kan, gbogbo wọn bá jọ jẹun níbi òkítì náà. Labani sọ ibẹ̀ ní Jegari Sahaduta, ṣugbọn Jakọbu pè é ní Galeedi. Labani wí pé, “Òkítì yìí ni ohun ẹ̀rí láàrin èmi pẹlu rẹ lónìí.” Nítorí náà ó sọ ọ́ ní Galeedi. Ó sì sọ ọ̀wọ̀n náà ní Misipa, nítorí ó wí pé, “Kí OLUWA ṣọ́ wa nígbà tí a bá pínyà lọ́dọ̀ ara wa. Bí o bá fi ìyà jẹ àwọn ọmọbinrin mi, tabi o tún fẹ́ obinrin mìíràn kún àwọn ọmọbinrin mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹnìkan pẹlu wa, ranti o, Ọlọrun ni ẹlẹ́rìí láàrin àwa mejeeji.” Labani bá sọ fún Jakọbu pé, “Wo òkítì ati ọ̀wọ̀n yìí, tí mo ti gbé kalẹ̀ láàrin àwa mejeeji. Òkítì yìí ati ọ̀wọ̀n yìí sì ni ẹ̀rí pẹlu pé n kò ní kọjá òkítì yìí láti wá gbógun tì ọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni ìwọ náà kò ní kọjá òkítì ati ọ̀wọ̀n yìí láti wá gbógun tì mí. Ọlọrun Abrahamu ati Ọlọrun Nahori, àní, Ọlọrun baba wọn ni onídàájọ́ láàrin wa.” Jakọbu náà bá búra ní orúkọ Ọlọrun tí Isaaki baba rẹ̀ ń sìn tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù. Jakọbu bá rúbọ lórí òkè náà, ó pe àwọn ìbátan rẹ̀ láti jẹun, wọ́n sì wà lórí òkè náà ní gbogbo òru ọjọ́ náà. Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, Labani fi ẹnu ko àwọn ọmọbinrin rẹ̀ ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ lẹ́nu láti dágbére fún wọn, ó súre fún wọn, ó sì pada sílé. Bí Jakọbu ti ń lọ ní ojú ọ̀nà, àwọn angẹli Ọlọrun pàdé rẹ̀. Nígbà tí Jakọbu rí wọn, ó ní, “Àwọn ọmọ ogun Ọlọrun nìyí.” Ó bá sọ ibẹ̀ ní Mahanaimu. Jakọbu rán àwọn oníṣẹ́ ṣáájú lọ sọ́dọ̀ Esau, ẹ̀gbọ́n rẹ̀, tí ó wà ní ilẹ̀ Seiri, ní agbègbè Edomu. Ó sọ fún wọn pé, “Ohun tí ẹ óo sọ fún Esau, oluwa mi nìyí, ẹ ní èmi, Jakọbu iranṣẹ rẹ̀, ní kí ẹ sọ fún un pé mo ti ṣe àtìpó lọ́dọ̀ Labani, ati pé ibẹ̀ ni mo sì ti wà títí di àkókò yìí. Ẹ ní mo ní àwọn mààlúù, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, agbo ẹran, àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin. Ẹ ní mo ní kí n kọ́ ranṣẹ láti sọ fún un ni, kí n lè rí ojurere lọ́dọ̀ rẹ̀.” Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ náà pada wá jábọ̀ fún Jakọbu, wọ́n sọ fún un pé, “A jíṣẹ́ rẹ fún Esau arakunrin rẹ, ó sì ń bọ̀ wá pàdé rẹ pẹlu irinwo (400) ọkunrin.” Ẹ̀rù ba Jakọbu gidigidi, ó sì dààmú, ó bá dá àwọn eniyan tí wọn wà pẹlu rẹ̀ ati agbo mààlúù, ati agbo aguntan ati àwọn ràkúnmí rẹ̀ sí ọ̀nà meji meji. Ó rò ninu ara rẹ̀ pé bí Esau bá dé ọ̀dọ̀ ìpín tí ó wà níwájú, tí ó bá sì pa wọ́n run, ìpín kan tí ó kù yóo sá àsálà. Jakọbu bá gbadura báyìí pé, “Ọlọrun Abrahamu baba mi, ati Ọlọrun Isaaki baba mi, Ọlọrun tí ó wí fún mi pé, ‘Pada sí ilẹ̀ rẹ ati sí ọ̀dọ̀ àwọn ìbátan rẹ, n óo sì ṣe ọ́ níre.’ N kò lẹ́tọ̀ọ́ sí èyí tí ó kéré jùlọ ninu ìfẹ́ ńlá rẹ tí kì í yẹ̀, ati òdodo tí o ti fihan èmi iranṣẹ rẹ, nítorí ọ̀pá lásán ni mo mú lọ́wọ́ nígbà tí mo gòkè odò Jọdani, ṣugbọn nisinsinyii, mo ti di ẹgbẹ́ ogun ńlá meji. Mo bẹ̀ ọ́, gbà mí lọ́wọ́ Esau arakunrin mi, nítorí ẹ̀rù rẹ̀ ń bà mí, kí ó má baà wá pa gbogbo wa, àtàwọn ìyá, àtàwọn ọmọ wọn. Ìwọ ni o ṣá sọ fún mi pé, ‘Ire ni n óo ṣe fún ọ, n óo sì sọ àwọn ọmọ rẹ di pupọ bí iyanrìn etí òkun tí ẹnikẹ́ni kò ní lè kà tán.’ ” Ó sùn níbẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ náà, ó sì mú ninu ohun ìní rẹ̀ láti fi ṣe ẹ̀bùn fún Esau arakunrin rẹ̀. Ó ṣa igba (200) ewúrẹ́ ati ogún òbúkọ, igba (200) aguntan, ati ogún àgbò, ọgbọ̀n abo ràkúnmí, tàwọn tọmọ wọn, ogoji abo mààlúù ati akọ mààlúù mẹ́wàá, ogún abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati akọ mẹ́wàá. Ó fi iranṣẹ kọ̀ọ̀kan ṣe olùtọ́jú agbo ẹran kọ̀ọ̀kan. Ó sọ fún àwọn iranṣẹ wọnyi pé, “Ẹ máa lọ ṣáájú mi, kí ẹ sì jẹ́ kí àlàfo wà láàrin agbo ẹran kan ati ekeji.” Ó sọ fún èyí tí ó ṣáájú patapata pé, “Nígbà tí Esau arakunrin mi bá pàdé rẹ, tí ó sì bi ọ́ pé, ‘Ti ta ni ìwọ í ṣe? Níbo ni ò ń lọ? Ta ló sì ni àwọn ẹran tí wọ́n wà níwájú rẹ?’ Kí o wí pé, ‘Ti Jakọbu iranṣẹ rẹ ni, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀bùn tí ó fi ranṣẹ sí Esau oluwa rẹ̀, òun alára ń bọ̀ lẹ́yìn.’ ” Bákan náà ni ó kọ́ ekeji ati ẹkẹta ati gbogbo àwọn iranṣẹ tí wọ́n tẹ̀lé àwọn agbo ẹran náà. Ó ní, “Nǹkan kan náà ni kí ẹ máa wí fún Esau, nígbà tí ẹ bá pàdé rẹ̀. Kí ẹ sì wí pé, ‘Jakọbu alára ń bọ̀ lẹ́yìn.’ ” Nítorí ó rò ninu ara rẹ̀ pé, bóyá òun lè fi àwọn ẹ̀bùn tí ó tì ṣáájú wọnyi tù ú lójú, àṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀, nígbà tí ojú àwọn mejeeji bá pàdé, bóyá yóo dáríjì òun. Nítorí náà, àwọn ẹ̀bùn ni ó kọ́ lọ ṣáájú rẹ̀, òun pàápàá sì dúró ninu àgọ́ ní alẹ́ ọjọ́ náà. Ní òru ọjọ́ náà gan an, ó dìde ó kó àwọn aya rẹ̀ mejeeji, àwọn iranṣẹbinrin mejeeji ati àwọn ọmọ rẹ̀ mọkọọkanla, ó kọjá sí ìhà keji odò Jaboku. Ó kó àwọn ati ohun gbogbo tí ó ní kọjá sí ìhà keji odò. Ó wá ku Jakọbu nìkan, ọkunrin kan bá a wọ ìjàkadì títí di àfẹ̀mọ́jú ọjọ́ keji. Nígbà tí ọkunrin náà rí i pé òun kò lè dá Jakọbu, ó fi ọwọ́ kan kòtò itan rẹ̀, eegun itan Jakọbu bá yẹ̀ níbi tí ó ti ń bá a jìjàkadì. Nígbà náà ni ó wí pé, “Jẹ́ kí n lọ nítorí ilẹ̀ ti ń mọ́” Ṣugbọn Jakọbu kọ̀, ó ní, “N kò ní jẹ́ kí o lọ, àfi bí o bá súre fún mi.” Ọkunrin náà bá bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni orúkọ rẹ?” Jakọbu dáhùn pé, “Jakọbu ni.” Ọkunrin náà bá dáhùn pé, “A kò ní pè ọ́ ní Jakọbu mọ́, Israẹli ni a óo máa pè ọ́, nítorí pé o ti bá Ọlọrun ati eniyan wọ ìjàkadì, o sì ti ṣẹgun.” Jakọbu bá bẹ̀ ẹ́, ó ní, “Jọ̀wọ́, sọ orúkọ rẹ fún mi.” Ṣugbọn ó dá a lóhùn pé, “Èéṣe tí o fi ń bèèrè orúkọ mi?” Ó bá súre fún Jakọbu níbẹ̀. Nítorí náà ni Jakọbu fi sọ ibẹ̀ ní Penieli, ó ní, “Mo ti rí Ọlọrun lojukooju, sibẹ mo ṣì wà láàyè.” Oòrùn yọ kí ó tó kọjá Penueli, nítorí pé títiro ni ó ń tiro lọ nítorí itan rẹ̀. Nítorí náà, títí di òní, àwọn ọmọ Israẹli kì í jẹ iṣan tí ó bo ihò itan níbi tí itan ti sopọ̀ mọ́ ìbàdí, nítorí pé ihò itan Jakọbu ni ọkunrin náà fọwọ́ kàn, orí iṣan tí ó so ó pọ̀ mọ́ ìbàdí. Bí Jakọbu ti gbé ojú sókè, ó rí Esau tí ń bọ̀ pẹlu irinwo (400) ọkunrin. Ó bá pín àwọn ọmọ rẹ̀ fún Lea ati Rakẹli, ati àwọn iranṣẹbinrin mejeeji. Ó ti àwọn iranṣẹbinrin ati àwọn ọmọ wọn ṣáájú, Lea ati àwọn ọmọ rẹ̀ sì tẹ̀lé wọn, Rakẹli ati Josẹfu ni wọ́n wà lẹ́yìn patapata. Jakọbu alára bá bọ́ siwaju gbogbo wọn, ó wólẹ̀ nígbà meje títí tí ó fi súnmọ́ Esau, arakunrin rẹ̀. Esau sáré pàdé rẹ̀, ó dì mọ́ ọn, ó so mọ́ ọn lọ́rùn, ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu, àwọn mejeeji sì sọkún. Nígbà tí Esau gbé ojú sókè, tí ó rí àwọn obinrin ati àwọn ọmọ, ó ní, “Ta ni àwọn wọnyi tí wọ́n wà pẹlu rẹ?” Jakọbu dáhùn, ó ní, “Àwọn ọmọ tí Ọlọrun fi ta èmi iranṣẹ rẹ lọ́rẹ ni.” Àwọn iranṣẹbinrin ati àwọn ọmọ wọn bá súnmọ́ wọn, wọ́n sì wólẹ̀ fún Esau. Lea ati àwọn ọmọ rẹ̀ náà súnmọ́ wọn, àwọn náà wólẹ̀ fún un, lẹ́yìn náà ni Josẹfu ati Rakẹli súnmọ́ ọn, àwọn náà wólẹ̀ fún un bákan náà. Ó bá bèèrè, ó ní, “Kí ni o ti fẹ́ ṣe gbogbo àwọn agbo ẹran tí mo pàdé lọ́nà?” Jakọbu dáhùn, ó ní, “Mo ní kí n fi wọ́n wá ojurere Esau, oluwa mi ni.” Ṣugbọn Esau dáhùn pé, “Èyí tí mo ní ti tó mi, arakunrin mi, máa fi tìrẹ sọ́wọ́.” Ṣugbọn Jakọbu dáhùn pé, “Rárá o, jọ̀wọ́, bí mo bá bá ojurere rẹ pàdé nítòótọ́ gba ẹ̀bùn tí mo mú wá lọ́wọ́ mi, nítorí pé rírí tí mo rí ojú rẹ tí inú rẹ sì yọ́ sí mi tó báyìí, ó dàbí ìgbà tí mo rí ojú Ọlọrun. Jọ̀wọ́ gba ẹ̀bùn tí mo mú wá fún ọ nítorí pé Ọlọrun ti ṣe oore fún mi lọpọlọpọ ati pé mo ní ànító.” Jakọbu rọ̀ ọ́ títí tí ó fi gbà á. Lẹ́yìn náà, Esau sọ fún Jakọbu pé, “Jẹ́ kí á múra kí á máa lọ n óo sì ṣáájú.” Ṣugbọn Jakọbu dá a lóhùn, ó ní, “Ṣebí oluwa mi mọ̀ pé àwọn ọmọ kò lágbára tóbẹ́ẹ̀ ati pé mo níláti ro ti àwọn ẹran tí wọ́n ní ọmọ wẹ́wẹ́ lẹ́yìn, bí a bá dà wọ́n ní ìdàkudà ní ọjọ́ kan péré, gbogbo agbo ni yóo run. Oluwa mi, máa lọ níwájú, n óo máa bọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ níwọ̀n bí ìrìn àwọn ẹran ati àwọn ọmọ bá ti lè yá mọ, títí tí n óo fi wá bá oluwa mi ní Seiri.” Esau bá ní, “Jẹ́ kí n fi àwọn bíi mélòó kan sílẹ̀ pẹlu rẹ ninu àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu mi.” Ṣugbọn Jakọbu dá a lóhùn pé, “Mo dúpẹ́, má wulẹ̀ ṣe ìyọnu kankan. Àní, kí n ṣá ti rí ojurere oluwa mi.” Esau bá yipada ní ọjọ́ náà, ó gbọ̀nà Seiri. Ṣugbọn Jakọbu lọ sí Sukotu o kọ́ ilé kan fún ara rẹ̀ ó sì ṣe àtíbàbà fún àwọn ẹran rẹ̀. Nítorí náà ni wọ́n Ṣe ń pe ibẹ̀ ní Sukotu. Nígbà tí ó yá, Jakọbu dé sí Ṣekemu ní ilẹ̀ Kenaani ní alaafia, nígbà tí ó ń pada ti Padani-aramu bọ̀ ó pàgọ́ rẹ̀ siwaju ìlú náà. Ó ra ilẹ̀ ibi tí ó pàgọ́ rẹ̀ sí ní ọgọrun-un (100) gẹsita lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hamori, baba Ṣekemu. Ó tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀, ó sì sọ pẹpẹ náà ní Eli-Ọlọrun-Israẹli. Ní ọjọ́ kan, Dina, ọmọbinrin tí Lea bí fún Jakọbu jáde lọ kí àwọn obinrin kan ní ìlú Ṣekemu. Nígbà tí Ṣekemu ọmọ Hamori, ará Hifi, tíí ṣe ọmọ ọba ìlú náà rí i, ó fi ipá mú un, ó sì bá a lòpọ̀ tipátipá. Ọkàn rẹ̀ fà sí Dina ọmọ Jakọbu, ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì sọ ọ̀rọ̀ rere fún un. Ṣekemu bá lọ sọ fún Hamori, baba rẹ̀, pé kí ó fẹ́ ọmọbinrin náà fún òun. Jakọbu ti gbọ́ pé ó ti ba Dina, ọmọ rẹ̀ jẹ́, ṣugbọn àwọn ọmọ rẹ̀ wà pẹlu àwọn ẹran ninu pápá, Jakọbu kò sọ nǹkankan títí tí wọ́n fi dé. Hamori baba Ṣekemu tọ Jakọbu wá láti bá a sọ̀rọ̀. Nígbà tí àwọn ọmọ Jakọbu pada dé sílé, tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, inú bí wọn gidigidi nítorí bíbá tí Ṣekemu bá Dina lòpọ̀ pẹlu ipá yìí jẹ́ ìwà àbùkù gbáà ní Israẹli, irú ìwà bẹ́ẹ̀ kò tọ́ sí ẹnikẹ́ni láti hù. Ṣugbọn Hamori bá wọn sọ̀rọ̀, ó ní, “Ọkàn Ṣekemu, ọmọ mi, fà sí arabinrin yín, ẹ jọ̀wọ́, ẹ fún un kí ó fi ṣe aya. Ẹ jẹ́ kí á jọ máa fẹ́ ọmọ lọ́wọ́ ara wa, ẹ máa fi àwọn ọmọbinrin yín fún wa, kí àwa náà máa fi àwọn ọmọbinrin wa fún yín. A óo jọ máa gbé pọ̀, ibi tí ó bá wù yín ni ẹ lè gbé, ibi tí ẹ bá fẹ́ ni ẹ ti lè ṣòwò, tí ẹ sì lè ní ohun ìní.” Ṣekemu tún wí fún baba ati àwọn arakunrin omidan náà pé, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ yọ́nú sí mi, ohunkohun tí ẹ bá ní kí n san, n óo san án. Iyekíye tí ó bá wù yín ni kí ẹ bèèrè fún owó orí iyawo, n óo san án, ẹ ṣá ti fi omidan náà fún mi.” Ọgbọ́n ẹ̀tàn ni àwọn ọmọ Jakọbu fi dá Ṣekemu ati Hamori, baba rẹ̀ lóhùn, nítorí bíbà tí ó ba Dina, arabinrin wọn jẹ́. Wọ́n wí fún wọn pé, “Ìtìjú gbáà ni ó jẹ́, pé kí a fi ọmọbinrin wa fún ẹni tí kò kọlà abẹ́, a kò gbọdọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ rárá. Ohun kan ṣoṣo tí ó lè mú kí ọ̀rọ̀ náà ṣeéṣe ni pé kí ẹ̀yin náà dàbí wa, kí gbogbo ọkunrin yín kọlà abẹ́. Nígbà náà ni a óo tó máa fi ọmọ wa fun yín tí àwa náà yóo máa fẹ́ ọmọ yín, a óo máa gbé pọ̀ pẹlu yín, a óo sì di ọ̀kan. Ṣugbọn bí ẹ bá kọ̀, tí ẹ kò gbà láti kọlà abẹ́, a óo mú ọmọbinrin wa, a óo sì máa lọ.” Ọ̀rọ̀ wọn dùn mọ́ Hamori ati Ṣekemu, ọmọ rẹ̀ ninu. Ọdọmọkunrin náà kò fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀, nítorí pé ó fẹ́ràn ọmọbinrin Jakọbu lọpọlọpọ. Ninu gbogbo ìdílé ọmọkunrin yìí, òun ni ó jẹ́ eniyan pataki jùlọ. Hamori ati Ṣekemu, ọmọ rẹ̀ bá lọ sí ẹnubodè ìlú, wọ́n sọ fún àwọn ọkunrin ìlú náà pé, “Ìbágbé àwọn eniyan wọnyi tuni lára pupọ, ẹ jẹ́ kí wọ́n máa gbé ilẹ̀ wa, kí wọ́n máa tà, kí wọ́n máa rà, ilẹ̀ yìí tóbi tó, ó gbà wọ́n. Ẹ jẹ́ kí á máa fẹ́ ọmọ lọ́wọ́ wọn, kí àwọn náà sì máa fẹ́ ọmọ lọ́wọ́ wa. Ohun kan ṣoṣo ni wọ́n ní kí á ṣe kí á lè jọ máa gbé pọ̀, kí á sì di ọ̀kan, wọ́n ní olukuluku ọkunrin wa gbọdọ̀ kọlà abẹ́ gẹ́gẹ́ bíi tiwọn. Ṣebí gbogbo ẹran ọ̀sìn wọn, ati gbogbo ohun ìní wọn ni yóo di tiwa? Ẹ ṣá jẹ́ kí á gbà fún wọn, wọn yóo sì máa bá wa gbé.” Gbogbo àwọn ará ìlú náà gba ohun tí Hamori ati Ṣekemu ọmọ rẹ̀ wí, gbogbo ọkunrin sì kọlà abẹ́. Ní ọjọ́ kẹta, nígbà tí ará kan wọ́n, meji ninu àwọn ọmọ Jakọbu, Simeoni ati Lefi, arakunrin Dina, mú idà wọn, wọ́n jálu àwọn ará ìlú náà lójijì, wọ́n sì pa gbogbo ọkunrin wọn. Wọ́n fi idà pa Hamori pẹlu, ati Ṣekemu ọmọ rẹ̀. Wọ́n mú Dina jáde kúrò ní ilé Ṣekemu, wọ́n sì bá tiwọn lọ. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Jakọbu wá kó gbogbo ohun ìní àwọn ará ìlú náà nítorí pé wọ́n ba arabinrin wọn jẹ́. Wọ́n kó gbogbo aguntan wọn, gbogbo mààlúù wọn, gbogbo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, ati gbogbo ohun tí ó wà nílé ati èyí tí ó wà ninu pápá. Ati gbogbo dúkìá wọn, àwọn ọmọ wọn ati àwọn aya wọn, gbogbo wọn ni wọ́n kó lẹ́rú, wọ́n sì kó gbogbo ohun tí ó wà ninu ilé wọn pẹlu. Jakọbu sọ fún Simeoni ati Lefi pé, “Irú ìyọnu wo ni ẹ kó mi sí yìí? Ẹ sọ mí di ọ̀tá gbogbo àwọn tí ń gbé ilẹ̀ yìí, láàrin àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Perisi. Àwa nìyí, a kò pọ̀ jù báyìí lọ. Tí wọ́n bá kó ara wọn jọ sí mi, wọn óo run mí tilé-tilé.” Ṣugbọn wọ́n dáhùn pé, “Àwa kò lè gbà kí ó ṣe arabinrin wa bí aṣẹ́wó.” Lẹ́yìn náà, Ọlọrun sọ fún Jakọbu pé, “Dìde, lọ sí Bẹtẹli kí o máa gbé ibẹ̀, kí o tẹ́ pẹpẹ kan fún Ọlọrun tí ó farahàn ọ́ nígbà tí ò ń sálọ fún Esau, arakunrin rẹ.” Jakọbu bá sọ fún gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ ati àwọn alábàágbé rẹ̀, pé, “Ẹ kó gbogbo ère oriṣa tí ń bẹ lọ́dọ̀ yín dànù, kí ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì pààrọ̀ aṣọ yín. Lẹ́yìn náà ẹ jẹ́ kí á lọ sí Bẹtẹli, kí n lè tẹ́ pẹpẹ kan sibẹ fún Ọlọrun, ẹni tí ó dá mi lóhùn ní ọjọ́ ìpọ́njú, tí ó sì wà pẹlu mi ní gbogbo ibi tí mo ti lọ.” Gbogbo wọn bá dá àwọn ère oriṣa tí ó wà lọ́wọ́ wọn jọ fún Jakọbu, ati gbogbo yẹtí tí ó wà ní etí wọn, Jakọbu bá bò wọ́n mọ́lẹ̀ lábẹ́ igi oaku tí ó wà ní Ṣekemu. Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn. Jìnnìjìnnì láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun sì dà bo gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní àyíká wọn, wọn kò sì lépa àwọn ọmọ Jakọbu. Jakọbu ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá wá sí Lusi, tí ó wà ní ilẹ̀ Kenaani, èyí nnì ni Bẹtẹli. Ó tẹ́ pẹpẹ kan sibẹ, ó sì sọ ibẹ̀ ní Eli-Bẹtẹli, nítorí pé níbẹ̀ ni Ọlọrun ti farahàn án nígbà tí ó ń sálọ fún arakunrin rẹ̀. Níbẹ̀ ni Debora, olùtọ́jú Rebeka kú sí, wọ́n sì sin ín sí abẹ́ igi oaku kan ní ìhà gúsù Bẹtẹli, Jakọbu bá sọ ibẹ̀ ní Aloni-bakuti. Ọlọrun tún fara han Jakọbu, nígbà tí ó jáde kúrò ní Padani-aramu, ó súre fún un. Ọlọrun wí fún un pé, “Jakọbu ni orúkọ rẹ, ṣugbọn wọn kò ní pè ọ́ ní Jakọbu mọ́, Israẹli ni orúkọ rẹ yóo máa jẹ́.” Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun ṣe sọ ọ́ ní Israẹli. Ọlọrun tún sọ fún un pé, “Èmi ni Ọlọrun Olodumare, máa bímọ lémọ, kí o sì pọ̀ sí i, ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ati ọpọlọpọ ọba ni yóo ti ara rẹ jáde. N óo fún ọ ní ilẹ̀ tí mo fún Abrahamu ati Isaaki, àwọn ọmọ rẹ ni yóo sì jogún rẹ̀.” Ọlọrun bá gòkè lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ níbi tí ó ti bá a sọ̀rọ̀. Jakọbu gbé ọ̀wọ̀n òkúta kan nàró níbẹ̀, ó fi ohun mímu rúbọ lórí òkúta náà, ó ta òróró sórí rẹ̀, Ó sì sọ ibẹ̀ ní Bẹtẹli. Wọ́n kúrò ní Bẹtẹli, nígbà tí ó kù díẹ̀ kí wọ́n dé Efurati ni ọmọ mú Rakẹli, ara sì ni ín gidigidi. Bí ó ti ń rọbí lọ́wọ́, agbẹ̀bí tí ń gbẹ̀bí rẹ̀ ń dá a lọ́kàn le pé, “Má bẹ̀rù, ọkunrin ni o óo tún bí.” Nígbà tí ẹ̀mí rẹ̀ ń bọ́ lọ, kí ó tó kú, ó sọ ọmọ náà ní Benoni, ṣugbọn baba rẹ̀ sọ ọ́ ní Bẹnjamini. Bẹ́ẹ̀ ni Rakẹli ṣe kú, wọ́n sì sin ín sí ẹ̀bá ọ̀nà Efurati, èyí nnì ni Bẹtilẹhẹmu. Jakọbu gbé ọ̀wọ̀n kan nàró lórí ibojì rẹ̀, òun ni wọ́n ń pè ní ọ̀wọ̀n ibojì Rakẹli, ó sì wà níbẹ̀ títí di òní. Jakọbu tún bẹ̀rẹ̀ sí bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ, ó pàgọ́ rẹ̀ sí òdìkejì ilé ìṣọ́ Ederi. Nígbà tí Israẹli ń gbé ibẹ̀, Reubẹni bá Biliha, aya baba rẹ̀ lòpọ̀, Jakọbu sì gbọ́ nípa rẹ̀. Àwọn ọmọ Jakọbu jẹ́ mejila. Àwọn tí Lea bí ni: Reubẹni, àkọ́bí Jakọbu. Lẹ́hìn rẹ̀ ni ó bí Simeoni, Lefi, Juda, Isakari ati Sebuluni. Àwọn tí Rakẹli bí ni: Josẹfu ati Bẹnjamini. Àwọn tí Biliha, iranṣẹbinrin Rakẹli bí ni: Dani ati Nafutali. Àwọn tí Silipa, iranṣẹbinrin Lea bí ni: Gadi ati Aṣeri. Àwọn wọnyi ni àwọn ọmọ tí wọ́n bí fún Jakọbu ní Padani-aramu. Jakọbu pada sọ́dọ̀ Isaaki, baba rẹ̀, ní Mamure, ìlú yìí kan náà ni wọ́n ń pè ní Kiriati Ariba tabi Heburoni, níbi tí Abrahamu ati Isaaki gbé. Isaaki jẹ́ ẹni ọgọsan-an (180) ọdún nígbà tí ó kú. Ó dàgbà, ó darúgbó lọpọlọpọ kí ó tó kú. Àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji, Esau ati Jakọbu, sì sin ín. Àkọsílẹ̀ ìran Esau, tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Edomu nìyí: Ninu àwọn ọmọbinrin Kenaani ni Esau ti fẹ́ aya, ekinni ń jẹ́ Ada, ọmọ Eloni ará Hiti, ekeji ń jẹ́ Oholibama, ọmọ Ana tí baba rẹ̀ ń jẹ́ Sibeoni, ará Hifi. Ẹkẹta ń jẹ́ Basemati ọmọ Iṣimaeli, arabinrin Nebaiotu. Ada bí Elifasi fún Esau, Basemati bí Reueli. Oholibama bí Jeuṣi, Jalamu ati Kora. Àwọn ni ọmọ Esau, tí àwọn aya rẹ̀ bí fún un ní ilẹ̀ Kenaani. Nígbà tí ó ṣe, Esau kó àwọn aya rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin, gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, àwọn mààlúù rẹ̀, àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀, ati gbogbo ohun ìní rẹ̀ tí ó ti kójọ ní ilẹ̀ Kenaani, ó kó kúrò ní ilẹ̀ Kenaani lọ́dọ̀ Jakọbu, arakunrin rẹ̀. Ìdí ni pé ọrọ̀ wọn ti pọ̀ ju kí wọ́n jọ máa gbé pọ̀ lọ, ilẹ̀ tí wọ́n sì ti ń ṣe àtìpó kò gbà wọ́n mọ́, nítorí pé wọ́n ní ẹran ọ̀sìn tí ó pọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni Esau ṣe di ẹni tí ń gbé orí òkè Seiri. Esau kan náà ni ń jẹ́ Edomu. Àkọsílẹ̀ ìran Esau, baba àwọn ará Edomu, tí ń gbé orí òkè Seiri nìyí: orúkọ àwọn ọmọ rẹ̀ ni, Elifasi, tí Ada bí, ati Reueli, tí Basemati bí. Àwọn ọmọ Elifasi ni: Temani, Omari, Sefo, Gatamu ati Kenasi. (Elifasi, ọmọ Esau ní obinrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Timna, òun ni ó bí Amaleki fún un.) Àwọn ni àwọn ọmọ Ada, aya Esau. Àwọn ọmọ Reueli ni Nahati, Sera, Ṣama, ati Misa. Àwọn ni àwọn ọmọ Basemati, aya Esau. Àwọn ọmọ tí Oholibama, ọmọ Ana, ọmọ Sibeoni, aya Esau, bí fún un ni Jeuṣi, Jalamu ati Kora. Àwọn tí wọ́n jẹ́ ìjòyè ninu àwọn ọmọ Esau nìwọ̀nyí, Lára àwọn ọmọ Elifasi, àkọ́bí Esau, tí Ada bí fún un: Temani, Omari, Sefo, Kenasi. Kora, Gatamu, ati Amaleki. Àwọn wọnyii jẹ́ ọmọ Ada, aya Esau. Lára àwọn ọmọ Reueli, ọmọ Esau, àwọn tí wọ́n jẹ́ ìjòyè ni: Nahati, Sera, Ṣama, ati Misa. Àwọn ni ìjòyè tí wọ́n ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Reueli, ní ilẹ̀ Edomu, wọ́n sì jẹ́ ọmọ Basemati, aya Esau. Lára àwọn ọmọ Oholibama, aya Esau: àwọn tí wọ́n jẹ́ ìjòyè ni: Jeuṣi, Jalamu, ati Kora. Àwọn ni ìjòyè tí wọ́n ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Oholibama, ọmọ Ana, aya Esau. Wọ́n jẹ́ ọmọ Esau, tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Edomu, àwọn sì ni ìjòyè tí wọ́n ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ṣẹ̀. Àwọn ọmọ Seiri ará Hori, tí ń gbé ilẹ̀ náà nìyí: àwọn ọmọ rẹ̀ ni: Lotani, Ṣobali, Sibeoni ati Ana, Diṣoni, Eseri, ati Diṣani, àwọn ni ìjòyè ní ilẹ̀ Hori, wọ́n sì jẹ́ ọmọ Seiri ní ilẹ̀ Edomu. Àwọn ọmọ Lotani ni Hori, ati Hemani, Timna ni arabinrin Lotani. Àwọn ọmọ Ṣobali ni Alfani, Manahati, Ebali, Ṣefo ati Onamu. Àwọn ọmọ Sibeoni ni Aya ati Ana. Ana yìí ni ó rí àwọn ìsun omi gbígbóná láàrin aginjù, níbi tí ó ti ń tọ́jú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Sibeoni, baba rẹ̀. Àwọn ọmọ Ana ni, Diṣoni ati Oholibama. Àwọn ọmọ Diṣoni ni Hemdani, Eṣibani, Itirani, ati Kerani. Àwọn ọmọ Eseri ni: Bilihani, Saafani, ati Akani. Àwọn ọmọ Diṣani ni: Usi ati Arani. Àwọn ìjòyè tí wọ́n ṣẹ̀ lára Hori nìwọ̀nyí: Lotani, Ṣobali, Sibeoni, Diṣoni, Eseri, ati Diṣani. Àwọn ìjòyè ilẹ̀ Hori, gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé ìdílé wọn ní ilẹ̀ Seiri. Àwọn ọba tí wọ́n jẹ ní ilẹ̀ Edomu kí ó tó di pé ẹnikẹ́ni jọba ní ilẹ̀ Israẹli nìwọ̀nyí: Bela, ọmọ Beori jọba ní Edomu, orúkọ ìlú rẹ̀ ni Dinhaba. Nígbà tí Bela kú, Jobabu, ọmọ Sera, ará Bosira gorí oyè. Nígbà tí Jobabu kú, Huṣamu ti ilẹ̀ Temani, gorí oyè. Nígbà tí Huṣamu kú, Hadadi, ọmọ Bedadi, tí ó ṣẹgun Midiani, ní ilẹ̀ Moabu gorí oyè, orúkọ ìlú tirẹ̀ ni Afiti. Nígbà tí Hadadi kú, Samila ti Masireka gorí oyè. Nígbà tí Samila kú, Ṣaulu ará Rehoboti lẹ́bàá odò Yufurate gorí oyè. Nígbà tí Ṣaulu kú, Baali Hanani, ọmọ Akibori gorí oyè. Nígbà tí Baali Hanani ọmọ Akibori kú, Hadadi gorí oyè, orúkọ ìlú tirẹ̀ ni Pau, orúkọ aya rẹ̀ ni Mehetabeli, ọmọ Matiredi, ọmọbinrin Mesahabu. Orúkọ àwọn ìjòyè tí wọ́n ṣẹ̀ lára Esau nìwọ̀nyí, gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn ati ìlú tí olukuluku ti jọba: Timna, Alfa, Jeteti, Oholibama, Ela, Pinoni, Kenasi, Temani, Mibisari, Magidieli ati Iramu. Àwọn ni ìjòyè ní Edomu, gẹ́gẹ́ bí ìlú wọn ní ilẹ̀ ìní wọn, Esau tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Edomu sì ni baba àwọn ará Edomu. Jakọbu ń gbé ilẹ̀ Kenaani, níbi tí àwọn baba rẹ̀ ti ṣe àtìpó. Àkọsílẹ̀ ìran Jakọbu nìyí: Josẹfu jẹ́ ọmọ ọdún mẹtadinlogun ó sì ń bá àwọn arakunrin rẹ̀ tọ́jú agbo ẹran ó wà lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Biliha ati àwọn ọmọ Silipa, àwọn aya baba rẹ̀. Josẹfu a sì máa sọ gbogbo àṣìṣe àwọn arakunrin rẹ̀ fún baba wọn. Israẹli fẹ́ràn Josẹfu ju gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù lọ, nítorí pé ó ti di arúgbó kí ó tó bí i, nítorí náà ó dá ẹ̀wù aláràbarà kan fún un. Nígbà tí àwọn arakunrin rẹ̀ yòókù rí i pé baba wọn fẹ́ràn Josẹfu ju àwọn lọ, wọ́n kórìíra rẹ̀, wọn kì í sì fi sùúrù bá a sọ̀rọ̀. Ní ọjọ́ kan, Josẹfu lá àlá kan, ó bá rọ́ àlá náà fún àwọn arakunrin rẹ̀, àlá yìí sì jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ kórìíra rẹ̀ sí i. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ gbọ́ àlá kan tí mo lá. Èmi pẹlu yín, a wà ní oko ní ọjọ́ kan, à ń di ìtí ọkà, mo rí i tí ìtí ọkà tèmi wà lóòró, ó dúró ṣánṣán, àwọn ìtí ọkà tiyín sì yí i ká, wọ́n ń foríbalẹ̀ fún un.” Àwọn arakunrin rẹ̀ bá bi í pé, “Ṣé o rò pé ìwọ ni yóo jọba lórí wa ni? Tabi o óo máa pàṣẹ lé wa lórí?” Wọ́n sì túbọ̀ kórìíra rẹ̀ sí i nítorí àlá tí ó lá ati nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó tún lá àlá mìíràn, ó sì tún rọ́ ọ fún àwọn arakunrin rẹ̀, ó ní, “Ẹ gbọ́, mo mà tún lá àlá mìíràn! Mo rí oòrùn, ati òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀ mọkanla ní ojú àlá, gbogbo wọn foríbalẹ̀ fún mi.” Nígbà tí ó rọ́ àlá náà fún baba rẹ̀ ati àwọn arakunrin rẹ̀. Baba rẹ̀ bá a wí, ó ní, “Irú àlá rándanràndan wo ni ò ń lá wọnyi? Ṣé èmi, ati ìyá rẹ, ati àwọn arakunrin rẹ yóo wá foríbalẹ̀ fún ọ ni?” Àwọn arakunrin rẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìlara rẹ̀, ṣugbọn baba rẹ̀ kò gbàgbé ọ̀rọ̀ náà, ó ń rò ó ní ọkàn rẹ̀. Ní ọjọ́ kan àwọn arakunrin rẹ̀ ń da agbo aguntan baba wọn lẹ́bàá Ṣekemu, Israẹli bá pe Josẹfu, ó ní, “Ǹjẹ́ Ṣekemu kọ́ ni àwọn arakunrin rẹ da ẹran lọ? Wò ó, wá kí n rán ọ sí wọn.” Josẹfu bá dáhùn pé, “Èmi nìyí.” Israẹli sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́, lọ bá mi wo alaafia àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ ati ti àwọn agbo ẹran wá, kí o sì tètè pada wá jíṣẹ́ fún mi.” Israẹli bá rán an láti àfonífojì Heburoni lọ sí Ṣekemu. Níbi tí ó ti ń rìn kiri ninu pápá ni ọkunrin kan bá rí i, ó bi í pé, “Kí ni ò ń wá?” Josẹfu dáhùn pé, “Àwọn arakunrin mi ni mò ń wá, jọ̀wọ́, ǹjẹ́ o mọ ibi tí wọ́n da agbo ẹran wọn lọ?” Ọkunrin náà dá a lóhùn pé, “Wọ́n ti kúrò níhìn-ín, mo gbọ́ tí wọn ń bá ara wọn sọ pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ sí Dotani.’ ” Josẹfu bá tún lépa wọn lọ sí Dotani, ó sì bá wọn níbẹ̀. Bí wọ́n ti rí i tí ó yọ lókèèrè, kí ó tilẹ̀ tó súnmọ́ ọ̀dọ̀ wọn, wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọn láti pa á. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wí fún ara wọn pé, “Ẹ wò ó, alálàá ni ó ń bọ̀ yìí! Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á pa á, kí á wọ́ ọ sinu kòtò kan, kí á sọ pé ẹranko burúkú kan ni ó pa á jẹ, kí á wá wò ó bí àlá rẹ̀ yóo ṣe ṣẹ.” Ṣugbọn nígbà tí Reubẹni gbọ́, ó gbà á kalẹ̀ lọ́wọ́ wọn, ó ní, “Ẹ má jẹ́ kí á pa á. Ẹ má ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, jíjù ni kí ẹ jù ú sinu kànga gbígbẹ láàrin aginjù yìí, ẹ má pa á lára rárá.” Ó fẹ́ fi ọgbọ́n yọ ọ́ lọ́wọ́ wọn, kí ó lè fi í ranṣẹ sí baba wọn pada. Bí Josẹfu ti dé ọ̀dọ̀ àwọn arakunrin rẹ̀, wọ́n fi ipá bọ́ ẹ̀wù aláràbarà rẹ̀ lọ́rùn rẹ̀, wọ́n gbé e jù sinu kànga kan tí kò ní omi ninu. Bí wọ́n ti jókòó tí wọ́n fẹ́ máa jẹun, ojú tí wọ́n gbé sókè, wọ́n rí ọ̀wọ́ àwọn ará Iṣimaeli kan, wọ́n ń bọ̀ láti Gileadi, wọ́n ń lọ sí Ijipti, àwọn ràkúnmí wọn ru turari, ìkunra olóòórùn dídùn ati òjíá. Juda bá sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀, ó ní, “Anfaani wo ni yóo jẹ́ fún wa bí a bá pa arakunrin wa, tí a sì bo ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀? Ẹ jẹ́ kí á tà á fún àwọn ará Iṣimaeli yìí. Ẹ má jẹ́ kí á pa á, nítorí arakunrin wa ni, ara kan náà ni wá.” Ọ̀rọ̀ náà sì dùn mọ́ àwọn arakunrin rẹ̀. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, àwọn oníṣòwò ará Midiani ń rékọjá lọ, wọ́n bá fa Josẹfu jáde láti inú kànga gbígbẹ náà, wọ́n sì tà á fún àwọn ará Iṣimaeli ní ogún owó fadaka. Àwọn ará Iṣimaeli sì mú Josẹfu lọ sí Ijipti. Nígbà tí Reubẹni pada dé ibi kànga gbígbẹ tí wọ́n ju Josẹfu sí, tí ó rí i pé kò sí níbẹ̀ mọ́, ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn. Ó pada lọ bá àwọn arakunrin rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ọmọ náà kò sí níbẹ̀? Mo gbé! Ibo ni n óo yà sí?” Wọ́n bá mú ọmọ ewúrẹ́ kan ninu agbo, wọ́n pa á, wọ́n sì ti ẹ̀wù Josẹfu bọ inú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Wọ́n bá fi ẹ̀wù aláràbarà náà ranṣẹ sí baba wọn, wọ́n ní, “Ohun tí a rí nìyí. Wò ó wò, bóyá ẹ̀wù ọmọ rẹ ni, tabi òun kọ́.” Jakọbu yẹ̀ ẹ́ wò, ó sì wí pé, “Ẹ̀wù ọmọ mi ni, ẹranko burúkú kan ti pa á, dájúdájú, ẹranko náà ti fa Josẹfu ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.” Jakọbu bá fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn, ó fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora, ó sì ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ fún ọpọlọpọ ọjọ́. Gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin lọ láti tù ú ninu, ṣugbọn ó kọ̀, kò gba ìpẹ̀, ó ní, “Ninu ọ̀fọ̀ ni n óo wọ inú ibojì lọ bá ọmọ mi.” Bẹ́ẹ̀ ni baba rẹ̀ sọkún rẹ̀. Àwọn ará Midiani tí wọ́n ra Josẹfu tà á fún Pọtifari, ará Ijipti, ọ̀kan ninu àwọn ìjòyè Farao. Pọtifari yìí ni olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin ọba. Kò pẹ́ pupọ lẹ́yìn náà ni Juda bá fi àwọn arakunrin rẹ̀ sílẹ̀, ó kó lọ sí ọ̀dọ̀ ará Adulamu kan tí wọn ń pè ní Hira. Níbẹ̀ ni Juda ti rí ọmọbinrin ará Kenaani kan, tí baba rẹ̀ ń jẹ́ Ṣua, ó gbé e níyàwó, ó sì bá a lòpọ̀. Ó lóyún, ó bí ọmọkunrin kan, Juda sọ ọmọ náà ní Eri. Ó tún lóyún, ó bí ọmọkunrin keji, ó sọ ọ́ ní Onani. Ó tún lóyún mìíràn, ó tún bí ọkunrin bákan náà, ó bá sọ ọmọ náà ní Ṣela. Ìlú Kẹsibu ni ó wà nígbà tí ó bí ọmọ náà. Juda fẹ́ aya fún Eri, àkọ́bí rẹ̀. Orúkọ obinrin náà ni Tamari. Ìwà Eri burú tóbẹ́ẹ̀ tí Ọlọrun fi pa á. Juda bá pe Onani, ó ní, “Ṣú iyawo arakunrin rẹ lópó kí o sì bá a lòpọ̀, kí ó lè bímọ fún arakunrin rẹ.” Ṣugbọn Onani mọ̀ pé ọmọ tí opó náà bá bí kò ní jẹ́ ti òun, nítorí náà, nígbàkúùgbà tí ó bá ń bá opó yìí lòpọ̀, yóo sì da nǹkan ọkunrin rẹ̀ sílẹ̀, kí ó má baà bí ọmọ tí yóo rọ́pò arakunrin rẹ̀. Ohun tí Onani ń ṣe yìí kò dùn mọ́ Ọlọrun ninu, Ọlọrun bá pa òun náà. Juda bá sọ fún Tamari opó ọmọ rẹ̀ pé, “Wá pada sí ilé baba rẹ kí o lọ máa ṣe opó níbẹ̀ títí tí Ṣela, ọmọ mi yóo fi dàgbà.” Ṣugbọn ọ̀rọ̀ tí Juda sọ yìí kò dé inú rẹ̀ nítorí ẹ̀rù ń bà á pé kí Ṣela náà má kú bí àwọn arakunrin rẹ̀, Tamari bá pada lọ sí ilé baba rẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, aya Juda, tíí ṣe ọmọ Ṣua kú. Nígbà tí Juda ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ parí, òun ati Hira ará Adulamu, ọ̀rẹ́ rẹ̀ bá múra, wọ́n lọ sí Timna lọ́dọ̀ àwọn tí wọn ń rẹ́ irun aguntan Juda. Àwọn kan lọ sọ fún Tamari pé baba ọkọ rẹ̀ ń lọ sí Timna láti rẹ́ irun aguntan rẹ̀. Tamari bá bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ kúrò lára, ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀, ó wọ aṣọ tí ó dára, ó bá jókòó lẹ́nu bodè Enaimu tí ó wà lọ́nà Timna; nítorí ó mọ̀ pé Ṣela ti dàgbà, wọn kò sì ṣú òun lópó fún un. Nígbà tí Juda rí Tamari tí ó fi aṣọ bojú, ó rò pé aṣẹ́wó ni. Ó tọ̀ ọ́ lọ níbi tí ó jókòó sí lẹ́bàá ọ̀nà, ó ní, “Wá, jẹ́ kí n bá ọ lòpọ̀,” kò mọ̀ pé opó ọmọ òun ni. Tamari dá a lóhùn, ó ní: “Kí ni o óo fún mi tí mo bá gbà fún ọ?” Juda dáhùn, ó ní, “N óo fi àwọ́nsìn ewúrẹ́ kan ranṣẹ sí ọ láti inú agbo ẹran mi.” Tamari ní, “O níláti fi nǹkankan dógò títí tí o óo fi fi ọmọ ewúrẹ́ náà ranṣẹ.” Juda bá bèèrè pé kí ni ó fẹ́ kí òun fi dógò. Ó dá a lóhùn, ó ní, “Èdìdì rẹ pẹlu okùn rẹ, ati ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ rẹ.” Juda bá kó wọn fún un, ó sì bá a lòpọ̀, Tamari sì lóyún. Ó dìde, ó bá tirẹ̀ lọ, ó ṣí ìbòjú rẹ̀ kúrò, ó sì tún wọ aṣọ ọ̀fọ̀ rẹ̀. Juda fi àwọ́nsìn ewúrẹ́ náà rán ọ̀rẹ́ rẹ̀, ará Adulamu, sí Tamari, kí ó le bá a gba àwọn ohun tí ó fi dógò lọ́wọ́ rẹ̀, ṣugbọn kò bá a níbẹ̀ mọ́. Ó bi àwọn ọkunrin kan, ará ìlú náà pé, “Níbo ni obinrin aṣẹ́wó tí ó máa ń jókòó ní gbangba lẹ́bàá ọ̀nà Enaimu yìí wà?” Wọ́n dáhùn pé, “Kò fi ìgbà kan sí aṣẹ́wó kankan ní àdúgbò yìí.” Ọ̀rẹ́ Juda bá pada tọ̀ ọ́ lọ, ó ní òun kò rí i, ati pé àwọn ọkunrin tí wọ́n wà níbẹ̀ sọ pé kò fi ìgbà kan sí aṣẹ́wó kankan níbẹ̀. Juda dá a lóhùn, ó ní, “Má wulẹ̀ wá a kiri mọ́, kí àwọn eniyan má baà máa fi wá ṣe yẹ̀yẹ́. Jẹ́ kí ó ṣe àwọn nǹkan ọwọ́ rẹ̀ bí ó bá ti fẹ́, mo ṣá fi àwọ́nsìn ewúrẹ́ tí mo ṣèlérí ranṣẹ, o kò rí i ni.” Lẹ́yìn bí oṣù mẹta sí i, ẹnìkan wá sọ fún Juda pé, “Wò ó! Iṣẹ́ aṣẹ́wó ni Tamari, opó ọmọ rẹ ń ṣe, ó sì ti lóyún.” Juda bá dáhùn, ó ní, “Ẹ lọ mú un wá kí wọ́n dáná sun ún.” Nígbà tí wọ́n mú un dé, ó ranṣẹ sí baba ọkọ rẹ̀, ó ní, “Ẹni tí ó ni àwọn nǹkan wọnyi ni ó fún mi lóyún. Jọ̀wọ́ yẹ̀ wọ́n wò, kí o mọ ẹni tí ó ni èdìdì yìí pẹlu okùn rẹ̀, ati ọ̀pá yìí.” Juda yẹ̀ wọ́n wò, ó sì mọ̀ wọ́n, ó ní, “O ṣe olóòótọ́ jù mí lọ, èmi ni mo jẹ̀bi nítorí pé n kò ṣú ọ lópó fún Ṣela, ọmọ mi.” Kò sì bá a lòpọ̀ mọ́. Nígbà tí ọjọ́ ìkúnlẹ̀ rẹ̀ pé, wọ́n rí i pé ìbejì ni ó wà ninu rẹ̀. Bí ó ti ń rọbí, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ náà yọ ọwọ́ jáde, ẹni tí ń bá a gbẹ̀bí bá so òwú pupa mọ́ ọn lọ́wọ́, ó ní “Èyí tí ó kọ́ jáde nìyí.” Ṣugbọn bí ọmọ náà ti fa ọwọ́ rẹ̀ pada, arakunrin rẹ̀ bá jáde. Agbẹ̀bí náà bá wí pé, “Ṣé bí o ti fẹ́ rìn nìyí, ó hàn lára rẹ.” Ó bá sọ orúkọ rẹ̀ ní Peresi. Láìpẹ́ arakunrin rẹ̀ náà wálẹ̀, pẹlu òwú pupa tí wọ́n so mọ́ ọn lọ́wọ́, wọ́n bá sọ ọ́ ní Sera. Àwọn ará Iṣimaeli mú Josẹfu lọ sí Ijipti, wọ́n sì tà á fún Pọtifari ará Ijipti. Pọtifari yìí jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ìjòyè Farao, òun sì tún ni olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin ọba. OLUWA wà pẹlu Josẹfu, ninu ilé ọ̀gá rẹ̀, ará Ijipti, níbi tí ó ń gbé. Àwọn ohun tí ó ń ṣe sì ń yọrí sí rere. Ọ̀gá rẹ̀ ṣàkíyèsí pé OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ati pé OLUWA ń bukun ohun gbogbo tí ó bá dáwọ́lé. Nítorí náà, ó rí ojurere Pọtifari. Pọtifari mú un sọ́dọ̀ pé kí ó máa ṣe iranṣẹ fún òun, ó fi ṣe alabojuto gbogbo ilé rẹ̀, ó sì fi ohun gbogbo tí ó ní sí ìkáwọ́ rẹ̀. Nígbà tí Pọtifari ti fi Josẹfu ṣe alabojuto ilé rẹ̀ ati gbogbo ohun ìní rẹ̀, OLUWA bẹ̀rẹ̀ sí bukun ìdílé Pọtifari, ará Ijipti náà, ati ohun gbogbo tí ó ní nítorí ti Josẹfu. Nítorí náà, ó fi ohun gbogbo tí ó ní sí ìkáwọ́ Josẹfu níwọ̀n ìgbà tí ó wà pẹlu rẹ̀, kò sì bìkítà fún ohunkohun mọ́, àfi oúnjẹ tí ó ń jẹ. Josẹfu ṣígbọnlẹ̀, ó sì lẹ́wà. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Josẹfu wu aya ọ̀gá rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀ ọ́ pé kí ó wá bá òun lòpọ̀. Ṣugbọn Josẹfu kọ̀, ó wí fún un pé, “Wò ó, níwọ̀n ìgbà tí mo wà lọ́dọ̀ ọ̀gá mi, kò bìkítà fún ohunkohun ninu ilé yìí, ó sì ti fi ohun gbogbo tí ó ní sí ìkáwọ́ mi. Kò sí ohun tí ó fi jù mí lọ ninu ilé yìí, kò sì sí ohun tí kò fi lé mi lọ́wọ́, àfi ìwọ nìkan, nítorí pé aya rẹ̀ ni ọ́. Ǹjẹ́ ó tọ́ sí mi láti ṣe irú ohun burúkú yìí kí n sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọrun?” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lojoojumọ ni ó ń rọ Josẹfu, sibẹsibẹ, Josẹfu kò gbà láti bá a lòpọ̀, tabi láti wà pẹlu rẹ̀. Ṣugbọn ní ọjọ́ kan nígbà tí Josẹfu wọ inú ilé lọ láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀, kò sí ẹnikẹ́ni nílé ninu àwọn ọkunrin tí wọn ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Obinrin yìí so mọ́ ọn lẹ́wù, ó ní, “Wá bá mi lòpọ̀.” Ṣugbọn Josẹfu bọ́rí kúrò ninu ẹ̀wù rẹ̀, ó sá jáde kúrò ninu ilé. Nígbà tí ó rí i pé Josẹfu fi ẹ̀wù rẹ̀ sílẹ̀ sí òun lọ́wọ́, ati pé ó sá jáde kúrò ninu ilé, ó pe àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ninu ilé rẹ̀, ó sọ fún wọn, ó ní, “Ẹ wo nǹkan, ọkọ mi ni ó mú Heberu yìí wá láti wá fi ẹ̀gbin lọ̀ wá. Ó wọlé wá bá mi láti bá mi lòpọ̀, ni mo bá pariwo. Nígbà tí ó sì rí i pé mo pariwo, ó sá jáde, ó fi ẹ̀wù rẹ̀ sílẹ̀ sí mi lọ́wọ́.” Obinrin náà bá fi ẹ̀wù rẹ̀ sọ́dọ̀ títí tí ọ̀gá rẹ̀ fi wọlé dé. Nígbà tí ó dé, obinrin yìí sọ ohun kan náà fún un, ó ní, “Ẹrú ará Heberu tí o mú wá sí ààrin wa, ni ó déédé wọlé tọ̀ mí wá láti fi ẹ̀gbin lọ̀ mí, ṣugbọn nígbà tí ó rí i pé mo pariwo, ó ju ẹ̀wù rẹ̀ sílẹ̀ sí mi lọ́wọ́, ó sá jáde.” Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí iyawo rẹ̀ sọ fún un pé, “Bí ẹrú rẹ ti ṣe sí mi nìyí” inú bí i gidigidi, ó sì sọ Josẹfu sinu ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ibi tí wọn ń ti àwọn tí ọba bá sọ sí ẹ̀wọ̀n mọ́ ni wọ́n tì í mọ́. Ṣugbọn OLUWA wà pẹlu Josẹfu, ó sì fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀ hàn sí i, ó jẹ́ kí ó bá ojurere alabojuto ọgbà ẹ̀wọ̀n náà pàdé. Alabojuto náà fi Josẹfu ṣe olùdarí gbogbo àwọn tí wọ́n wà ninu ẹ̀wọ̀n, ohunkohun tí Josẹfu bá sọ, ni wọ́n ń ṣe. Alabojuto ọgbà ẹ̀wọ̀n náà kì í fi nǹkan lé Josẹfu lọ́wọ́ kí ó tún bìkítà fún un mọ́, nítorí pé OLUWA wà pẹlu Josẹfu, ohunkohun tí ó bá ṣe, OLUWA ń jẹ́ kí ó yọrí sí rere. Ní àkókò kan, agbọ́tí Farao, ọba Ijipti, ati olórí alásè rẹ̀ ṣẹ ọba. Inú bí Farao sí àwọn iranṣẹ rẹ̀ mejeeji yìí, ó sì jù wọ́n sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ní ilé olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin ninu ọgbà ẹ̀wọ̀n tí Josẹfu wà. Alabojuto ọgbà ẹ̀wọ̀n náà fi wọ́n sábẹ́ àkóso Josẹfu, wọ́n sì wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n náà fún ìgbà díẹ̀. Ní òru ọjọ́ kan, agbọ́tí ọba ati olórí alásè náà lá àlá kan, àlá tí olukuluku lá sì ní ìtumọ̀ tirẹ̀. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́ tí Josẹfu rí wọn, ó rí i pé ọkàn wọn dàrú. Ó bá bi wọ́n pé, “Èéṣe tí ojú yín fi rẹ̀wẹ̀sì lónìí?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “A lá àlá kan ni, a kò sì rí ẹni bá wa túmọ̀ rẹ̀.” Josẹfu dá wọn lóhùn, ó ní, “Ṣebí Ọlọrun ni ó ni ìtumọ̀ àlá? Ẹ rọ́ àlá náà fún mi.” Agbọ́tí bá rọ́ àlá tirẹ̀ fún Josẹfu, ó ní, “Mo rí ìtàkùn àjàrà kan lójú àlá. Ìtàkùn náà ní ẹ̀ka mẹta, bí ewé rẹ̀ ti yọ, lẹsẹkẹsẹ, ni ó tanná, ó so, èso rẹ̀ sì pọ́n. Ife Farao wà ní ọwọ́ mi, mo bá mú èso àjàrà náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí fún un sinu ife Farao, mo sì gbé ife náà lé Farao lọ́wọ́.” Josẹfu bá sọ fún un pé, “Ìtumọ̀ rẹ̀ nìyí: àwọn ẹ̀ka mẹta tí o rí dúró fún ọjọ́ mẹta. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹta Farao yóo yọ ọ́ jáde, yóo dáríjì ọ́, yóo sì fi ọ́ sí ipò rẹ pada, o óo sì tún máa gbé ọtí fún Farao bíi ti àtẹ̀yìnwá. Ṣugbọn ṣá o, ranti mi nígbà tí ó bá dára fún ọ, jọ̀wọ́, ṣe mí lóore kan, ròyìn mi fún Farao, kí Farao sì yọ mí kúrò ninu àhámọ́ yìí. Nítorí pé jíjí ni wọ́n jí mi gbé kúrò ní ilẹ̀ Heberu, ati pé níhìn-ín gan-an, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ṣẹ̀ tí wọ́n fi gbé mi jù sẹ́wọ̀n yìí.” Alásè rí i pé ìtumọ̀ rẹ̀ dára, ó wí fún Josẹfu pé, “Èmi náà lá àlá kan, mo ru agbọ̀n àkàrà mẹta lórí, lójú àlá. Mo rí i pé oríṣìíríṣìí oúnjẹ Farao ni ó wà ninu agbọ̀n tí ó wà ní òkè patapata, mo bá tún rí i tí àwọn ẹyẹ bẹ̀rẹ̀ sí jẹ àwọn oúnjẹ yìí ní orí mi.” Josẹfu dáhùn, ó ní, “Ìtumọ̀ rẹ̀ nìyí: àwọn agbọ̀n mẹta náà dúró fún ọjọ́ mẹta. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹta, Farao ọba yóo yọ ọ́ jáde níhìn-ín, yóo bẹ́ ọ lórí, yóo gbé ọ kọ́ igi, àwọn ẹyẹ yóo sì jẹ ẹran ara rẹ.” Ní ọjọ́ kẹta tíí ṣe ọjọ́ ìbí Farao, ọba se àsè ńlá fún gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó sì mú agbọ́tí rẹ̀ ati alásè rẹ̀ jáde sí ààrin àwọn iranṣẹ rẹ̀. Ó dá agbọ́tí pada sí ipò rẹ̀ láti máa gbé ọtí fún un, ṣugbọn ó pàṣẹ kí wọ́n lọ so olórí alásè kọ́ igi, gẹ́gẹ́ bí Josẹfu ti túmọ̀ àlá wọn fún wọn. Ṣugbọn olórí agbọ́tí kò ranti Josẹfu mọ, ó gbàgbé rẹ̀ patapata. Lẹ́yìn ọdún meji gbáko, Farao náà wá lá àlá pé òun dúró létí odò Naili. Ó rí àwọn mààlúù meje kan tí wọ́n sanra rọ̀pọ̀tọ̀ rọ̀pọ̀tọ̀, tí ara wọ́n sì ń dán, wọ́n ti inú odò náà jáde wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ koríko létí odò. Rírí tí yóo tún rí, ó rí àwọn mààlúù meje mìíràn, wọ́n tún ti inú odò náà jáde wá, àwọn wọnyi rù hangangan, wọ́n rí jàpàlà jàpàlà, wọ́n dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn meje ti àkọ́kọ́. Àwọn meje tí wọ́n rù hangangan náà ki àwọn meje tí wọ́n sanra rọ̀pọ̀tọ̀ rọ̀pọ̀tọ̀ mọ́lẹ̀, wọ́n sì gbé wọn mì, Farao bá tají. Ó tún sùn, ó sì lá àlá mìíràn, rírí tí yóo tún rí, ó rí ṣiiri ọkà meje lórí ẹyọ igi ọkà kan, wọ́n tóbi, wọ́n sì yọmọ. Ó sì tún rí i tí ṣiiri ọkà meje mìíràn yọ lẹ́yìn wọn, wọ́n tínínrín, wọn kò sì ní ọmọ ninu rárá, nítorí afẹ́fẹ́ ìhà ìlà oòrùn ti pa ọlá mọ́ wọn lára. Àwọn ṣiiri ọkà tínínrín meje náà gbé àwọn meje tí wọ́n yọmọ mì. Farao bá tún tají, ó sì tún rí i pé àlá ni òun ń lá. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ìdààmú bá Farao, ó bá ranṣẹ lọ pe gbogbo àwọn adáhunṣe ati àwọn amòye ilẹ̀ Ijipti, ó rọ́ àlá náà fún wọn, kò sì sí ẹnìkan ninu wọn tí ó lè túmọ̀ rẹ̀ fún un. Nígbà náà ni agbọ́tí sọ fún Farao pé, “Mo ranti ẹ̀ṣẹ̀ mi lónìí. Nígbà tí inú fi bí ọba sí àwa iranṣẹ rẹ̀ meji, tí ọba sì gbé èmi ati alásè jù sẹ́wọ̀n ní ilé olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin, àwa mejeeji lá àlá ní òru ọjọ́ kan náà, olukuluku àlá tí a lá ni ó sì ní ìtumọ̀. Ọdọmọkunrin Heberu kan wà níbẹ̀ pẹlu wa, ó jẹ́ iranṣẹ olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin, nígbà tí a rọ́ àlá wa fún un, ó túmọ̀ wọn fún wa. Bí olukuluku wa ti lá àlá tirẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ó túmọ̀ wọn. Gẹ́gẹ́ bí ó ti túmọ̀ àlá wa, bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó sì rí. Ọba dá mi pada sí ààyè mi, ó sì pàṣẹ kí wọ́n so alásè kọ́.” Farao bá ranṣẹ lọ pe Josẹfu, wọ́n sì mú un jáde kúrò ninu ẹ̀wọ̀n kíá. Lẹ́yìn tí ó fá irun rẹ̀, tí ó sì pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó wá siwaju Farao. Farao sọ fún un pé, “Mo lá àlá kan, kò sì tíì sí ẹni tí ó lè túmọ̀ rẹ̀. Wọ́n bá sọ fún mi pé, bí o bá gbọ́ àlá, o óo lè túmọ̀ rẹ̀.” Josẹfu dá Farao lóhùn, ó ní, “Kò sí ní ìkáwọ́ mi, Ọlọrun ni yóo fún kabiyesi ní ìdáhùn rere.” Farao bá sọ fún Josẹfu pé, “Wò ó, lójú àlá, bí mo ti dúró létí bèbè odò Naili, mo rí i tí àwọn mààlúù meje kan tí wọ́n sanra rọ̀pọ̀tọ̀ rọ̀pọ̀tọ̀, tí ara wọn sì ń dán, ti inú odò náà jáde wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ koríko létí odò. Àwọn mààlúù meje mìíràn tún jáde láti inú odò náà, gbogbo wọn rù hangangan, wọ́n rí jàpàlà jàpàlà, n kò rí irú rẹ̀ rí ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti. Àwọn mààlúù tí wọ́n rù wọnyi gbé àwọn tí wọ́n sanra mì. Nígbà tí wọ́n gbé wọn mì tán, eniyan kò lè mọ̀ rárá pé wọ́n jẹ ohunkohun, nítorí pé wọ́n tún rù hangangan bákan náà ni. Mo bá tají. Mo tún lá àlá lẹẹkeji, mo rí ṣiiri ọkà meje lórí igi ọkà kan, wọ́n tóbi, wọ́n sì yọmọ. Mo tún rí i tí ṣiiri ọkà meje mìíràn yọ lẹ́yìn wọn, wọ́n tínínrín, wọn kò sì ní ọmọ ninu rárá, nítorí afẹ́fẹ́ ìhà ìlà oòrùn ti pa ọlá mọ́ wọn lára. Àwọn ṣiiri ọkà tí kò níláárí wọnyi gbé àwọn tí wọ́n dára mì. Mo rọ́ àwọn àlá mi fún àwọn adáhunṣe, ṣugbọn kò sí ẹnìkan tí ó lè túmọ̀ wọn fún mi.” Josẹfu sọ fún Farao, ó ní, “Ọ̀kan náà ni àlá mejeeji, Ọlọrun fi ohun tí ó fẹ́ ṣe han kabiyesi ni. Àwọn mààlúù rọ̀pọ̀tọ̀ rọ̀pọ̀tọ̀ meje nnì ati àwọn ṣiiri ọkà meje tí wọ́n yọmọ dúró fún ọdún meje. Ọ̀kan náà ni àwọn àlá mejeeji. Àwọn mààlúù meje tí wọ́n rù, tí wọ́n sì rí jàpàlà jàpàlà tí wọ́n jáde lẹ́yìn àwọn ti àkọ́kọ́, ati àwọn ṣiiri ọkà meje tí kò yọmọ, tí afẹ́fẹ́ ìhà ìlà oòrùn ti pa ọlá mọ́ lára, àwọn náà dúró fún ìyàn ọdún meje. Bí ọ̀rọ̀ ti rí gan-an ni mo sọ fún kabiyesi yìí, Ọlọrun ti fi ohun tí ó fẹ́ ṣe han kabiyesi. Ọdún meje kan ń bọ̀ tí oúnjẹ yóo pọ̀ yanturu ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti, ṣugbọn lẹ́yìn náà ìyàn yóo mú fún ọdún meje, ìyàn náà yóo pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ọdún meje tí oúnjẹ pọ̀ yóo di ìgbàgbé ní ilẹ̀ Ijipti, ìyàn náà yóo run ilẹ̀ yìí. Ẹnikẹ́ni kò sì ní mọ̀ pé oúnjẹ ti fi ìgbà kan pọ̀ rí, nítorí ìyàn ńlá tí yóo tẹ̀lé e yóo burú jáì. Ìdí tí àlá kabiyesi náà fi jẹ́ meji ni láti fihàn pé Ọlọrun ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, láìpẹ́, Ọlọrun yóo mú un ṣẹ. “Bí ọ̀rọ̀ ti rí yìí, ó yẹ kí kabiyesi yan ọkunrin kan tí ó gbọ́n, tí ó sì lóye, kí ó fi ṣe olórí ní ilẹ̀ Ijipti. Kí kabiyesi yan àwọn alabojuto ní ilẹ̀ náà kí wọ́n kó ìdámárùn-ún ìkórè ilẹ̀ Ijipti jọ láàrin ọdún meje tí ọ̀pọ̀ oúnjẹ yóo fi wà. Kí wọ́n kó gbogbo oúnjẹ wọnyi jọ ninu ọdún tí oúnjẹ yóo pọ̀, kí wọ́n sì kó wọn pamọ́ sinu àwọn ìlú ńláńlá, pẹlu àṣẹ kabiyesi, kí wọ́n sì máa ṣọ́ ọ. Oúnjẹ yìí ni àwọn eniyan yóo máa jẹ láàrin ọdún meje tí ìyàn yóo mú ní ilẹ̀ Ijipti, kí ilẹ̀ náà má baà parun ní àkókò ìyàn náà.” Ìmọ̀ràn náà dára lójú Farao ati àwọn iranṣẹ rẹ̀. Ó bá sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ a lè rí irú ọkunrin yìí, ẹni tí ẹ̀mí Ọlọrun ń gbé inú rẹ̀?” Farao bá sọ fún Josẹfu pé, “Níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé ìwọ ni Ọlọrun fi gbogbo nǹkan yìí hàn, kò sí ẹni tí ó gbọ́n, tí ó sì lóye bíi rẹ. Ìwọ ni yóo máa ṣe olórí ilé mi, gbogbo àṣẹ tí o bá sì pa ni àwọn eniyan mi yóo tẹ̀lé, kìkì pé mo jẹ́ ọba nìkan ni n óo fi jù ọ́ lọ.” Farao bá sọ fún Josẹfu pé, “Wò ó! Mo fi ọ́ ṣe alákòóso ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti.” Farao bá bọ́ òrùka èdìdì ọwọ́ rẹ̀, ó fi bọ Josẹfu lọ́wọ́, ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ funfun olówó iyebíye, ó sì fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn. Farao ní kí Josẹfu gun ọkọ̀ ogun rẹ̀ keji gẹ́gẹ́ bí igbákejì ọba, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí hó níwájú rẹ̀ pé, “Ẹ yàgò lọ́nà!” Bẹ́ẹ̀ ni Farao ṣe fi Josẹfu ṣe olórí, ní ilẹ̀ Ijipti. Farao tún sọ fún un pé, “Èmi ni Farao, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe ohunkohun ní ilẹ̀ Ijipti láìjẹ́ pé o fọwọ́ sí i.” Lẹ́yìn náà ó sọ Josẹfu ní orúkọ Ijipti kan, orúkọ náà ni Safenati Panea, ó sì fi Asenati, ọmọ Pọtifera, fún un láti fi ṣe aya. Pọtifera yìí jẹ́ babalóòṣà oriṣa Oni, ní ìlú Heliopolisi. Josẹfu sì lọ káàkiri ilẹ̀ Ijipti. Josẹfu jẹ́ ọmọ ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lábẹ́ Farao, ọba Ijipti. A máa lọ láti ààfin ọba Farao káàkiri gbogbo ilẹ̀ Ijipti. Láàrin ọdún meje tí ọ̀pọ̀ oúnjẹ wà, ilẹ̀ so èso lọpọlọpọ. Josẹfu bẹ̀rẹ̀ sí kó oúnjẹ jọ fún ọdún meje tí oúnjẹ fi pọ̀ yanturu ní ilẹ̀ Ijipti, ó ń pa wọ́n mọ́ sinu àwọn ìlú ńláńlá. Gbogbo oúnjẹ tí wọ́n bá rí kójọ ní agbègbè ìlú ńlá kọ̀ọ̀kan, Josẹfu a kó o pamọ́ sinu ìlú ńlá náà. Bẹ́ẹ̀ ni Josẹfu ṣe kó ọkà jọ jantirẹrẹ bíi yanrìn etí òkun. Nígbà tó yá, òun gan-an kò mọ ìwọ̀n ọkà náà mọ́, nítorí pé ó ti pọ̀ kọjá wíwọ̀n. Asenati, ọmọ Pọtifera, babalóòṣà Oni, bí ọkunrin meji fún Josẹfu kí ìyàn tó bẹ̀rẹ̀. Josẹfu sọ ọmọ rẹ̀ kinni ní Manase, ó ní, “Ọlọ́run ti mú mi gbàgbé gbogbo ìnira mi ati ilé baba mi.” Ó sọ ọmọ keji ní Efuraimu, ó ní, “Ọlọrun ti mú mi bí sí i ní ilẹ̀ tí mo ti rí ìpọ́njú.” Nígbà tí ó yá, ọdún meje tí ọ̀pọ̀ oúnjẹ wà ní Ijipti dópin. Ọdún meje ìyàn sì bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Josẹfu ti wí, ìyàn mú ní ilẹ̀ gbogbo, ṣugbọn oúnjẹ wà ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti. Nígbà tí oúnjẹ kò sí mọ́ ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti, àwọn eniyan náà kígbe tọ Farao lọ fún oúnjẹ. Farao sọ fún gbogbo wọn pé, “Ẹ tọ Josẹfu lọ, ohunkohun tí ó bá wí fun yín ni kí ẹ ṣe.” Nígbà tí ìyàn náà tàn káàkiri gbogbo ilẹ̀, Josẹfu ṣí àwọn àká tí wọ́n kó oúnjẹ pamọ́ sí, ó ń ta oúnjẹ fún àwọn ará Ijipti, nítorí ìyàn náà mú gidigidi ní ilẹ̀ náà. Gbogbo ayé ni ó sì ń wá sọ́dọ̀ Josẹfu ní Ijipti tí wọ́n wá ra oúnjẹ, nítorí pé ìyàn náà mú gidigidi ní gbogbo ayé. Nígbà tí Jakọbu gbọ́ pé ọkà wà ní ilẹ̀ Ijipti, ó wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Kí ni ẹ̀ ń wo ara yín fún? Ẹ wò ó, mo gbọ́ pé ọkà wà ní Ijipti, ẹ lọ ra ọkà wá níbẹ̀ kí ebi má baà pa wá kú.” Àwọn arakunrin Josẹfu mẹ́wàá bá lọ sí Ijipti, wọ́n lọ ra ọkà. Ṣugbọn Jakọbu kò jẹ́ kí Bẹnjamini, arakunrin Josẹfu bá àwọn arakunrin rẹ̀ lọ, nítorí ẹ̀rù ń bà á kí nǹkankan má tún lọ ṣẹlẹ̀ sí òun náà. Àwọn ọmọ Israẹli lọ ra ọkà pẹlu àwọn mìíràn tí wọ́n wá ra ọkà, nítorí kò sí ibi tí ìyàn náà kò dé ní ilẹ̀ Kenaani. Ní gbogbo àkókò yìí, Josẹfu ni gomina ilẹ̀ Ijipti, òun ni ó ń ta ọkà fún àwọn eniyan láti gbogbo orílẹ̀-èdè. Nígbà tí àwọn arakunrin rẹ̀ dé, wọ́n kí i, wọ́n wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Josẹfu rí àwọn arakunrin rẹ̀, ó sì mọ̀ wọ́n, ṣugbọn ó bá wọn sọ̀rọ̀ pẹlu ohùn líle bí ẹni pé kò mọ̀ wọ́n rí, ó ní, “Níbo ni ẹ ti wá?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Láti ilẹ̀ Kenaani ni, oúnjẹ ni a wá rà.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Josẹfu mọ̀ dájú pé àwọn arakunrin òun ni wọ́n, wọn kò mọ̀ ọ́n. Josẹfu wá ranti àlá rẹ̀ tí ó lá nípa wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Amí ni yín, ibi tí àìlera ilẹ̀ yìí wà ni ẹ wá yọ́ wò.” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Rárá o, oluwa mi, oúnjẹ ni àwa iranṣẹ rẹ wá rà. Ọmọ baba kan náà ni gbogbo wa, olóòótọ́ eniyan sì ni wá, a kì í ṣe amí.” Josẹfu tún sọ fún wọn pé, “N kò gbà, ibi tí àìlera ilẹ̀ yìí wà ni ẹ wá yọ́ wò.” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀bẹ̀, wọ́n ní, “Ọkunrin mejila ni àwa iranṣẹ rẹ, tí a jẹ́ ọmọ baba kan náà ní ilẹ̀ Kenaani, èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn wa wà lọ́dọ̀ baba wa nílé, ọ̀kan yòókù ti kú.” Ṣugbọn Josẹfu tẹnumọ́ ọn pé, “Bí mo ti wí gan-an ni ọ̀rọ̀ rí, amí ni yín. Ohun tí n óo fi mọ̀ pé olóòótọ́ ni yín nìyí: mo fi orúkọ Farao búra, ẹ kò ní jáde níhìn-ín àfi bí ẹ bá mú àbíkẹ́yìn baba yín wá. Ẹ rán ọ̀kan ninu yín kí ó lọ mú àbíkẹ́yìn yín wá, ẹ̀yin yòókù ẹ óo wà ninu ẹ̀wọ̀n títí a óo fi mọ̀ bóyá òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, mo tún fi orúkọ Farao búra, amí ni yín.” Ó bá da gbogbo wọn sinu ọgbà ẹ̀wọ̀n fún ọjọ́ mẹta. Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹta, Josẹfu wí fún wọn pé, “Mo bẹ̀rù Ọlọrun, nítorí náà, bí ẹ bá ṣe ohun tí n óo sọ fun yín yìí, n óo dá ẹ̀mí yín sí. Tí ó bá jẹ́ pé olóòótọ́ eniyan ni yín, kí ọ̀kan ninu yín wà ninu ẹ̀wọ̀n, kí ẹ̀yin yòókù ru ọkà lọ sí ilé fún ìdílé yín tí ebi ń pa, kí ẹ wá mú àbíkẹ́yìn yín tí ẹ̀ ń wí wá, kí n rí i, kí á lè mọ̀ pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yín, ẹ óo sì wà láàyè.” Wọ́n bá gbà bẹ́ẹ̀. Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn sọ̀rọ̀ pé, “Dájúdájú, a jẹ̀bi arakunrin wa, nítorí pé a rí ìdààmú ọkàn rẹ̀ nígbà tí ó ń bẹ̀ wá, ṣugbọn a kò dá a lóhùn, ohun tí ó fà á nìyí tí ìdààmú yìí fi dé bá wa.” Reubẹni bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Mo sọ fun yín àbí n kò sọ, pé kí ẹ má fi ohunkohun ṣe ọmọ náà? Ṣugbọn ẹ kọ̀, ẹ kò gbọ́, òun nìyí nisinsinyii, ẹ̀san ni ó dé yìí.” Wọn kò mọ̀ pé Josẹfu gbọ́ gbogbo ohun tí wọn ń wí, nítorí pé ògbufọ̀ ni wọ́n fi ń bá ara wọn sọ̀rọ̀. Josẹfu bá kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó lọ sọkún, ó tún pada wá láti bá wọn sọ̀rọ̀. Ó mú Simeoni láàrin wọn, ó dè é lókùn. Josẹfu pàṣẹ pé kí wọ́n di ọkà sinu àpò olukuluku wọn, kí ó kún, kí wọ́n dá owó olukuluku pada sinu àpò rẹ̀, kí wọ́n sì fún wọn ní oúnjẹ tí wọn yóo jẹ lójú ọ̀nà. Wọ́n ṣe fún wọn bí Josẹfu ti wí. Wọ́n di ẹrù wọn ru àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, wọ́n sì gbọ̀nà ilé. Nígbà tí wọ́n dé ibi tí wọn yóo sùn lálẹ́ ọjọ́ náà, ọ̀kan ninu wọn tú àpò rẹ̀ láti fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní oúnjẹ, ó bá rí owó rẹ̀ tí wọ́n dì sí ẹnu àpò rẹ̀. Ó wí fún àwọn arakunrin rẹ̀ pé, “Wọ́n dá owó mi pada, òun nìyí lẹ́nu àpò mi yìí.” Nígbà tí wọ́n gbọ́ bẹ́ẹ̀, ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, wọ́n ń wo ara wọn lójú, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n, wọ́n ní, “Irú kí ni Ọlọrun ṣe sí wa yìí?” Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jakọbu baba wọn ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n kó gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn, wọ́n rò fún un, wọ́n ní, “Ọkunrin tíí ṣe alákòóso ilẹ̀ náà sọ̀rọ̀ líle sí wa, ó ṣebí a wá ṣe amí ilẹ̀ náà ni. Ṣugbọn a wí fún un pé, ‘Olóòótọ́ ni wá, a kì í ṣe eniyankeniyan, ati pé a kì í ṣe amí rárá. Ọkunrin mejila ni àwa tí a jẹ́ ọmọ baba kan náà, ọ̀kan ninu wa ti kú, èyí tí ó kéré jù sì wà lọ́dọ̀ baba wa ní ilẹ̀ Kenaani.’ Ọkunrin náà bá dáhùn pé, ohun tí yóo jẹ́ kí òun mọ̀ pé olóòótọ́ eniyan ni wá ni pé kí á fi ọ̀kan ninu wa sílẹ̀ lọ́dọ̀ òun, kí á gbé ọkà lọ sílé, kí ebi má baà pa ìdílé wa. Kí á mú àbúrò wa patapata wá fún òun, nígbà náà ni òun yóo tó mọ̀ pé a kì í ṣe amí, ati pé olóòótọ́ eniyan ni wá, òun óo sì dá arakunrin wa pada fún wa, a óo sì ní anfaani láti máa ṣòwò ní ilẹ̀ Kenaani.” Bí wọ́n ti tú àpò wọn, olukuluku bá owó rẹ̀ lẹ́nu àpò rẹ̀. Nígbà tí àwọn ati baba wọn rí èyí, àyà wọn já. Jakọbu baba wọn bá sọ fún wọn, ó ní, “Ẹ ti jẹ́ kí n ṣòfò àwọn ọmọ mi: Josẹfu ti kú, Simeoni kò sí mọ́, ẹ tún fẹ́ mú Bẹnjamini lọ. Èmi nìkan ni gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ sí tán!” Reubẹni bá wí fún baba rẹ̀ pé, “Pa àwọn ọmọ mi mejeeji, bí n kò bá mú Bẹnjamini pada wá fún ọ. Fi lé mi lọ́wọ́, n óo sì mú un pada wá fún ọ.” Ṣugbọn Jakọbu dáhùn, ó ní, “Ọmọ tèmi kò ní bá yín lọ, nítorí pé ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan ni ó kù. Bí ohunkohun bá ṣẹlẹ̀ sí i ní ìrìn àjò tí ẹ fẹ́ lọ yìí, mo ti darúgbó, ìbànújẹ́ rẹ̀ ni yóo rán mi sọ́run.” Ìyàn tí ó mú ní ilẹ̀ Kenaani ṣá túbọ̀ ń pọ̀ sí i ni. Nígbà tí wọ́n jẹ ọkà tí wọ́n rà ní Ijipti tán, baba wọn pè wọ́n, ó ní, “Ẹ tún wá lọ ra oúnjẹ díẹ̀ sí i.” Ṣugbọn Juda dá a lóhùn, ó ní, “Ọkunrin náà kìlọ̀ fún wa gidigidi pé a kò ní fi ojú kan òun láìjẹ́ pé a mú arakunrin wa lọ́wọ́. Bí o bá jẹ́ kí arakunrin wa bá wa lọ, a óo lọ ra oúnjẹ wá fún ọ, ṣugbọn bí o kò bá jẹ́ kí ó bá wa lọ, a kò ní lọ, nítorí pé ọkunrin náà tẹnumọ́ ọn fún wa pé a kò ní fi ojú kan òun láìjẹ́ pé arakunrin wa bá wa wá.” Israẹli ní, “Irú ọ̀ràn ńlá wo ni ẹ tún dá sí mi lọ́rùn yìí, tí ẹ lọ sọ fún ọkunrin náà pé ẹ ní arakunrin mìíràn?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Kò sí ohun tí ọkunrin náà kò bi wá tán nípa ará ati ẹbí wa, ó ní, ‘Ǹjẹ́ baba yín wà láàyè? Ǹjẹ́ ẹ tún ní arakunrin mìíràn?’ Àwọn ìbéèrè tí ó ń bèèrè ni ó mú kí á sọ ohun tí a sọ fún un. Báwo ni a ṣe lè mọ̀ pé yóo sọ pé kí á mú àbúrò wa wá?” Juda bá sọ fún Israẹli, ó ní, “Fa ọmọ náà lé mi lọ́wọ́, a óo sì lọ kí á lè wà láàyè, kí ebi má baà pa ẹnikẹ́ni kú ninu wa, ati àwọn ọmọ wa kéékèèké. N óo dúró fún ọmọ náà, ọwọ́ mi ni kí o ti bèèrè rẹ̀. Bí n kò bá mú un pada, kí n sì fà á lé ọ lọ́wọ́, da ẹ̀bi rẹ̀ lé mi lórí títí lae, nítorí pé bí a kò bá fi ìrìn àjò yìí falẹ̀ ni, à bá ti lọ, à bá sì ti dé, bí ẹẹmeji.” Israẹli, baba wọn bá sọ fún wọn pé, “Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ó dára, báyìí ni kí ẹ ṣe, ẹ dì ninu àwọn èso tí ó dára jùlọ ní ilẹ̀ yìí sinu àpò yín, kí ẹ gbé e lọ fún ọkunrin náà. Ẹ mú ìpara díẹ̀, oyin díẹ̀, turari díẹ̀ ati òjíá díẹ̀, ẹ mú èso pistakio ati èso alimọndi pẹlu. Ìlọ́po meji owó ọjà tí ẹ óo rà ni kí ẹ mú lọ́wọ́, ẹ mú owó tí ó wà lẹ́nu àpò yín níjelòó lọ́wọ́ pẹlu, bóyá wọ́n gbàgbé ni. Ẹ mú arakunrin yín náà lọ́wọ́, kí ẹ sì tọ ọkunrin náà lọ. Kí Ọlọrun Olodumare jẹ́ kí ọkunrin náà ṣàánú yín, kí ó sì dá arakunrin yín kan yòókù ati Bẹnjamini pada. Bí mo bá tilẹ̀ wá ṣòfò àwọn ọmọ mi nígbà náà, n óo gbà pé mo ṣòfò wọn.” Àwọn ọkunrin náà bá gbé ẹ̀bùn náà, wọ́n sì mú ìlọ́po meji owó tí wọ́n nílò, ati Bẹnjamini, wọ́n lọ siwaju Josẹfu ní Ijipti. Nígbà tí Josẹfu rí Bẹnjamini pẹlu wọn, ó sọ fún alabojuto ilé rẹ̀, ó ní, “Mú àwọn ọkunrin wọnyi wọlé, pa ẹran kan kí o sì sè é, nítorí wọn yóo bá mi jẹun lọ́sàn-án yìí.” Ọkunrin náà ṣe bí Josẹfu ti pàṣẹ fún un, ó sì mú àwọn ọkunrin náà wọ ilé Josẹfu lọ. Ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí bà wọ́n nígbà tí Josẹfu mú wọn wọ ilé rẹ̀, wọ́n ń wí fún ara wọn pé, “Nítorí owó tí wọ́n fi sí ẹnu àpò wa níjelòó ni wọ́n fi kó wa wọlé, kí ó lè rí ẹ̀sùn kà sí wa lẹ́sẹ̀, kí ó lè fi wá ṣe ẹrú, kí ó sì kó àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa.” Wọ́n bá tọ alabojuto ilé Josẹfu lọ lẹ́nu ọ̀nà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀bẹ̀, wọ́n ní, “Jọ̀wọ́ oluwa mi, a ti kọ́kọ́ wá ra oúnjẹ níhìn-ín nígbà kan. Nígbà tí à ń pada lọ tí a dé ibi tí a fẹ́ sùn, a tú àpò wa, olukuluku wa bá owó tirẹ̀ lẹ́nu àpò rẹ̀, kò sí ti ẹni tí ó dín rárá, a mú owó náà lọ́wọ́ báyìí. A sì tún mú owó mìíràn lọ́wọ́ pẹlu láti ra oúnjẹ. A kò mọ ẹni tí ó dá owó wa pada sinu àpò wa.” Ó dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ fọkàn yín balẹ̀, ẹ má bẹ̀rù, ó níláti jẹ́ pé Ọlọrun yín ati ti baba yín ni ó fi owó náà sinu àpò yín fun yín, mo gba owó lọ́wọ́ yín.” Ó bá mú Simeoni jáde sí wọn. Ọkunrin náà mú wọn wọ inú ilé Josẹfu, ó fún wọn ní omi, wọ́n fọ ẹsẹ̀ wọn, wọ́n sì fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn ní oúnjẹ. Lẹ́yìn náà wọ́n tọ́jú ẹ̀bùn Josẹfu sílẹ̀ di ìgbà tí yóo dé lọ́sàn-án, nítorí wọ́n gbọ́ pé ibẹ̀ ni wọn yóo ti jẹun. Nígbà tí Josẹfu wọlé, wọ́n mú ẹ̀bùn tí wọ́n mú bọ̀ fún un wọlé tọ̀ ọ́ lọ, wọ́n sì wólẹ̀ fún un, wọ́n dojúbolẹ̀. Ó bèèrè alaafia wọn, ó ní, “Ṣé alaafia ni baba yín wà, arúgbó tí ẹ sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún mi? Ṣé ó ṣì wà láàyè?” Wọ́n dá a lóhùn, wọ́n ní, “Baba wa, iranṣẹ rẹ ń bẹ láàyè, ó sì wà ní alaafia.” Wọ́n tẹríba, wọ́n bu ọlá fún un. Ojú tí ó gbé sókè, ó rí Bẹnjamini ọmọ ìyá rẹ̀, ó bá bèèrè pé, “Ṣé arakunrin yín tí í ṣe àbíkẹ́yìn tí ẹ wí nìyí? Kí Ọlọrun fi ojurere wò ọ́, ọmọ mi.” Josẹfu bá yára jáde kúrò lọ́dọ̀ wọn nítorí pé ọkàn rẹ̀ fà sí àbúrò rẹ̀, orí rẹ̀ sì wú, ó wá ibìkan láti lọ sọkún. Ó bá wọ yàrá rẹ̀, ó lọ sọkún níbẹ̀. Lẹ́yìn náà ó bọ́ ojú rẹ̀, ó jáde, ó gbìyànjú, ó dárayá, ó ní, “Ẹ gbé oúnjẹ wá.” Wọ́n gbé oúnjẹ tirẹ̀ kalẹ̀ lọ́tọ̀, ti àwọn arakunrin rẹ̀ lọ́tọ̀, ati ti àwọn ará Ijipti tí wọn ń bá a jẹun lọ́tọ̀, nítorí pé ìríra ni ó jẹ́ fún àwọn ará Ijipti láti bá àwọn Heberu jẹun pọ̀. Àwọn arakunrin Josẹfu jókòó níwájú rẹ̀, wọ́n tò wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí wọn, láti orí ẹ̀gbọ́n patapata dé orí àbúrò patapata. Nígbà tí àwọn arakunrin Josẹfu rí i bí wọ́n ti tò wọ́n, wọ́n ń wo ara wọn lójú tìyanu-tìyanu. Láti orí tabili Josẹfu ni wọ́n ti bu oúnjẹ fún olukuluku, ṣugbọn oúnjẹ ti Bẹnjamini tó ìlọ́po marun-un ti ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn. Wọ́n bá a jẹ, wọ́n mu, wọ́n sì bá a ṣe àríyá. Josẹfu pàṣẹ fún alabojuto ilé rẹ̀, ó ní, “Ẹ di ọkà kún àpò àwọn ọkunrin wọnyi, bí wọ́n bá ti lè rù tó, kí ẹ sì fi owó olukuluku wọn sí ẹnu àpò rẹ̀, kí ẹ wá fi ife fadaka mi sí ẹnu àpò èyí àbíkẹ́yìn wọn, pẹlu owó tí ó fi ra ọkà.” Ọkunrin náà sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Josẹfu ti pàṣẹ fún un. Bí ilẹ̀ ọjọ́ keji ti mọ́, wọ́n ní kí àwọn arakunrin Josẹfu máa lọ ati àwọn ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn. Nígbà tí wọn kò tíì rìn jìnnà sí ìlú, Josẹfu sọ fún alabojuto ilé rẹ̀ pé, “Gbéra, sáré tẹ̀lé àwọn ọkunrin náà, nígbà tí o bá bá wọn, wí fún wọn pé, ‘Èéṣe tí ẹ fi fi ibi sú olóore? Èéṣe tí ẹ fi jí ife fadaka ọ̀gá mi? Ife yìí ni ọ̀gá mi fi ń mu omi, ife yìí kan náà ni ó sì fi ń woṣẹ́, ọ̀ràn ńlá gan-an ni ẹ dá yìí.’ ” Nígbà tí ó lé wọn bá, ó wí fún wọn bí Josẹfu ti kọ́ ọ. Wọ́n dá a lóhùn, wọ́n ní, “Èéṣe tí o fi ń sọ̀rọ̀ sí wa báyìí? Kí á má rí i, pé àwa iranṣẹ rẹ ṣe ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀. Ṣé o ranti pé owó tí a bá lẹ́nu àpò wa, a mú un pada ti ilẹ̀ Kenaani wá fún ọ? Kí ni ìbá dé tí a óo fi jí fadaka tabi wúrà ní ilé ọ̀gá rẹ? Bí wọ́n bá bá a lọ́wọ́ èyíkéyìí ninu àwa iranṣẹ rẹ, pípa ni kí wọ́n pa olúwarẹ̀, kí àwa yòókù sì di ẹrú rẹ.” Ó dá wọn lóhùn, ó ní, “Bí ẹ ti wí gan-an ni yóo rí. Ọwọ́ ẹni tí a bá ti bá a ni yóo di ẹrú mi, kò sí ohun tí ó kan ẹ̀yin yòókù rárá.” Gbogbo wọn bá sọ àpò wọn kalẹ̀, wọ́n tú wọn. Iranṣẹ náà bá bẹ̀rẹ̀ sí wo àpò wọn, ó bẹ̀rẹ̀ lórí àpò èyí àgbà patapata, títí dé orí ti àbíkẹ́yìn wọn, wọ́n bá ife náà ninu ẹrù Bẹnjamini. Wọ́n fa aṣọ wọn ya láti fi ìbànújẹ́ wọn hàn, olukuluku wọn bá di ẹrù rẹ̀ ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, wọ́n pada lọ sí ààrin ìlú. Nígbà tí Juda ati àwọn arakunrin rẹ̀ pada dé ilé Josẹfu, ó ṣì wà nílé, wọ́n bá dọ̀bálẹ̀ gbalaja níwájú rẹ̀. Josẹfu bi wọ́n léèrè, ó ní, “Irú kí ni ẹ dánwò yìí? Ó jọ bí ẹni pé ẹ kò lérò pé irú mi lè woṣẹ́ ni?” Juda dá a lóhùn, ó ní, “Kí ni a rí tí a lè wí fún ọ, oluwa mi? Ọ̀rọ̀ wo ni ó lè dùn lẹ́nu wa? Ọṣẹ wo ni a lè fi wẹ̀, tí a fi lè mọ́? Ọlọrun ti rí ẹ̀bi àwa iranṣẹ rẹ. Wò ó, a di ẹrú rẹ, oluwa mi, ati àwa ati ẹni tí wọ́n bá ife náà lọ́wọ́ rẹ̀.” Ṣugbọn ó dá wọn lóhùn, ó ní, “Kí á má rí i pé mo ṣe ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀. Ẹnìkan ṣoṣo tí wọ́n ká ife náà mọ́ lọ́wọ́ ni yóo di ẹrú mi, ní tiyín, ẹ máa pada tọ baba yín lọ ní alaafia.” Juda bá tọ̀ ọ́ lọ, ó ní, “Jọ̀wọ́, oluwa mi, jẹ́ kí n sọ gbolohun ọ̀rọ̀ kan, má jẹ́ kí inú bí ọ sí èmi, iranṣẹ rẹ, nítorí kò sí ìyàtọ̀, bíi Farao ni o rí. Oluwa mi, ranti pé o bi àwa iranṣẹ rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ ẹ ní baba tabi arakunrin mìíràn?’ A sì dá oluwa mi lóhùn pé, ‘A ní baba, ó ti di arúgbó, a sì ní arakunrin kan pẹlu, tí baba yìí fi arúgbó ara bí, ati pé ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan ṣoṣo ni ó kù lọ́mọ ìyá tirẹ̀, baba rẹ̀ sì fẹ́ràn rẹ̀.’ O sọ fún àwa iranṣẹ rẹ pé kí á mú un tọ̀ ọ́ wá, kí o lè fi ojú rí i. A sì sọ fún ọ pé, ‘Ọmọ náà kò lè fi baba rẹ̀ sílẹ̀, nítorí pé bí ó bá fi baba rẹ̀ sílẹ̀, baba rẹ̀ yóo kú.’ O bá sọ fún àwa iranṣẹ rẹ pé bí àbíkẹ́yìn wa patapata kò bá bá wa wá, a kò ní rí ojú rẹ nílẹ̀ mọ́. “Nígbà tí a pada dé ọ̀dọ̀ baba wa, iranṣẹ rẹ, a rò fún un bí o ti wí. Nígbà tí ó ní kí á tún lọ ra oúnjẹ díẹ̀ wá, a wí fún un pé, a kò ní lọ, àfi bí arakunrin wa bá tẹ̀lé wa, nítorí pé a kò ní rí ojú rẹ nílẹ̀ bí kò bá bá wa wá. Baba wa sọ fún wa pé a mọ̀ pé ọkunrin meji ni Rakẹli, aya òun bí fún òun, ọ̀kan fi òun sílẹ̀, òun sì wí pé, dájúdájú, ẹranko kan ti fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, òun kò sì tíì fi ojú òun kàn án láti ìgbà náà. Ó ní bí a bá tún mú eléyìí kúrò lọ́dọ̀ òun, bí ohun burúkú kan bá ṣẹlẹ̀ sí i, pẹlu arúgbó ara òun yìí, ìbànújẹ́ rẹ̀ ni yóo pa òun. “Nítorí náà, bí mo bá pada dé ọ̀dọ̀ baba mi tí n kò sì mú ọmọdekunrin náà lọ́wọ́, níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé ọmọdekunrin yìí gan-an ni ó fi ẹ̀mí tẹ̀, bí kò bá rí i pẹlu wa, kíkú ni yóo kú. Yóo sì wá jẹ́ pé àwa ni a fa ìbànújẹ́ fún baba wa, ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, ìbànújẹ́ yìí ni yóo sì pa á. Èmi ni mo dúró fún ọmọdekunrin náà lọ́dọ̀ baba wa, mo wí fún un pé, ‘Bí n kò bá mú ọmọ yìí pada, ẹ̀bi rẹ̀ yóo wà lórí mi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi.’ Nígbà tí ọ̀rọ̀ wá rí bí ó ti rí yìí, oluwa mi, jọ̀wọ́, jẹ́ kí èmi di ẹrú rẹ dípò ọmọdekunrin yìí, jẹ́ kí òun máa bá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ pada lọ. Báwo ni n óo ṣe pada dé iwájú baba mi láìmú ọmọ náà lọ́wọ́? Ẹ̀rù ohun burúkú tí yóo ṣẹlẹ̀ sí baba mi, ń bà mí.” Josẹfu kò lè mú ọ̀rọ̀ yìí mọ́ra mọ́ lójú gbogbo àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀, ó bá kígbe, ó ní, “Gbogbo yín patapata, ẹ jáde kúrò lọ́dọ̀ mi.” Nítorí náà, kò sí ẹnikẹ́ni lọ́dọ̀ Josẹfu nígbà tí ó fi ara rẹ̀ han àwọn arakunrin rẹ̀ pé òun ni Josẹfu. Ó bú sẹ́kún, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pohùnréré ẹkún tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ará Ijipti ati gbogbo ilé Farao gbọ́ ẹkún rẹ̀. Josẹfu sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀ pé òun ni Josẹfu. Ó bi wọ́n léèrè pé ǹjẹ́ baba òun ṣì wà láàyè. Ṣugbọn jìnnìjìnnì dà bo àwọn arakunrin rẹ̀ níwájú rẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò lè dáhùn. Josẹfu bá bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀ wọ́n, ó ní kí wọ́n jọ̀wọ́, kí wọ́n súnmọ́ òun. Ó tún wí fún wọn pé òun ni Josẹfu arakunrin wọn, tí wọ́n tà sí Ijipti. Ó ní, “Ẹ má wulẹ̀ dààmú ẹ̀mí ara yín, ẹ má sì bínú sí ara yín pé ẹ tà mí síhìn-ín. Ọlọrun fúnrarẹ̀ ni ó rán mi ṣáájú yín láti gba ẹ̀mí là. Nítorí ó ti di ọdún keji tí ìyàn yìí ti bẹ̀rẹ̀ ní ilẹ̀ yìí, ó sì ku ọdún marun-un gbáko tí kò fi ní sí ìfúrúgbìn tabi ìkórè. Ọlọrun ni ó rán mi ṣáájú yín láti dá yín sí, ati láti gba ọpọlọpọ ẹ̀mí là ninu ìran yín. Nítorí náà, kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ gbé mi dé ìhín, Ọlọrun ni, ó sì ti fi mí ṣe baba fún Farao, ati oluwa ninu gbogbo ilé rẹ̀ ati alákòóso gbogbo ilẹ̀ Ijipti. “Ẹ ṣe kíá, ẹ wá lọ sọ́dọ̀ baba mi kí ẹ wí fún un pé, Josẹfu ọmọ rẹ̀ wí pé, Ọlọrun ti fi òun ṣe olórí ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti, ẹ ní mo ní kí ó máa bọ̀ lọ́dọ̀ mi kíákíá. Ẹ sọ fún un pé mo sọ pé kí ó wá máa gbé ní ilẹ̀ Goṣeni nítòsí mi, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, ati agbo mààlúù rẹ̀, ati ohun gbogbo tí ó ní. N óo máa tọ́jú rẹ̀ níbẹ̀, nítorí pé ó tún ku ọdún marun-un gbáko kí ìyàn yìí tó kásẹ̀ nílẹ̀, kí òun ati ìdílé rẹ̀ ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ má baà di aláìní. “Ẹ̀yin pàápàá fi ojú rí i, Bẹnjamini arakunrin mi náà sì rí i pẹlu pé èmi gan-an ni mò ń ba yín sọ̀rọ̀. Ẹ níláti sọ fún baba mi nípa gbogbo ògo mi ní Ijipti, ati gbogbo ohun tí ẹ ti rí. Ẹ tètè yára mú baba mi wá bá mi níhìn-ín.” Ó bá rọ̀ mọ́ Bẹnjamini arakunrin rẹ̀ lọ́rùn, ó sì bú sẹ́kún, bí Bẹnjamini náà ti rọ̀ mọ́ ọn, ni òun náà bú sẹ́kún. Josẹfu bá fi ẹnu ko àwọn arakunrin rẹ̀ lẹ́nu lọ́kọ̀ọ̀kan, ó sì sọkún, lẹ́yìn náà ni àwọn arakunrin rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí bá a sọ̀rọ̀. Nígbà tí gbogbo ìdílé Farao gbọ́ pé àwọn arakunrin Josẹfu dé, inú Farao ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ dùn pupọ. Farao sọ fún Josẹfu pé kí ó sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀ kí wọ́n múra, kí wọ́n di ẹrù ru àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, kí wọ́n tètè pada lọ sí Kenaani, kí wọ́n sì lọ mú baba rẹ̀ ati gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ wá sọ́dọ̀ òun. Ó ní òun óo fún un ní ibi tí ó dára jùlọ ní ilẹ̀ Ijipti, wọn yóo sì jẹ àjẹyó ninu ilẹ̀ náà. Ó ní kí Josẹfu pàṣẹ fún wọn pẹlu kí wọ́n kó kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin láti ilẹ̀ Ijipti, láti fi kó àwọn ọmọde ati àwọn obinrin, kí baba wọn náà sì máa bá wọn bọ̀. Ó ní kí wọ́n má ronú àwọn dúkìá wọn nítorí àwọn ni wọn yóo ni ilẹ̀ tí ó dára jù ní Ijipti. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe bí ọba ti wí, Josẹfu fún wọn ní kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Farao, ó sì fún wọn ní oúnjẹ tí wọn yóo máa jẹ lọ́nà. Ó fún olukuluku wọn ní ìpààrọ̀ aṣọ kọ̀ọ̀kan, ṣugbọn ó fún Bẹnjamini ní ọọdunrun (300) ṣekeli fadaka ati ìpààrọ̀ aṣọ marun-un. Ó di àwọn nǹkan dáradára ilẹ̀ Ijipti ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá, ó di ọkà ati oúnjẹ ru abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá, ó kó wọn ranṣẹ sí baba rẹ̀ pé kí ó rí ohun máa jẹ bọ̀ lọ́nà. Ó bá ní kí àwọn arakunrin òun máa lọ, bí wọ́n sì ti fẹ́ máa lọ, ó kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n má bá ara wọn jà lọ́nà. Wọ́n bá kúrò ní Ijipti, wọ́n pada sọ́dọ̀ Jakọbu baba wọn ní ilẹ̀ Kenaani. Wọ́n sọ fún un pé, “Josẹfu kò kú, ó wà láàyè, ati pé òun ni alákòóso gbogbo ilẹ̀ Ijipti.” Nígbà tí ó gbọ́ bẹ́ẹ̀, orí rẹ̀ fò lọ fee, kò kọ́ gbà wọ́n gbọ́. Ṣugbọn nígbà tí ó gbọ́ gbogbo ohun tí Josẹfu wí fún wọn, tí ó tún rí kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin tí Josẹfu fi ranṣẹ pé kí wọ́n fi gbé òun wá, ara rẹ̀ wálẹ̀. Israẹli bá dáhùn, ó ní, “Josẹfu, ọmọ mi wà láàyè! Ó ti parí, n óo lọ fi ojú kàn án kí n tó kú.” Israẹli di gbogbo ohun tí ó ní, ó kó lọ sí Beeriṣeba, ó lọ rúbọ sí Ọlọrun Isaaki, baba rẹ̀. Ọlọrun bá a sọ̀rọ̀ lójú ìran lóru, ó pè é, ó ní, “Jakọbu, Jakọbu.” Ó dáhùn, ó ní, “Èmi nìyí.” Ọlọrun wí pé, “Èmi ni Ọlọrun baba rẹ, má fòyà rárá láti lọ sí Ijipti, nítorí pé n óo sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá níbẹ̀. N óo bá ọ lọ sí Ijipti, n óo sì tún mú ọ pada wá, ọwọ́ Josẹfu ni o óo sì dákẹ́ sí.” Jakọbu bá bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ̀ láti Beeriṣeba. Àwọn ọmọ rẹ̀ gbé e sinu ọkọ̀ tí Farao fi ranṣẹ sí i pé kí wọ́n fi gbé e wá, wọ́n sì kó àwọn iyawo wọn ati àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ pẹlu wọn. Wọ́n kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ati gbogbo ohun tí wọ́n ní ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n lọ sí Ijipti. Gbogbo ilé rẹ̀ patapata ni Jakọbu kó lọ́wọ́ lọ sí Ijipti, ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, lọkunrin ati lobinrin, gbogbo wọn ni ó kó lọ sí Ijipti patapata. Ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ ati àwọn ọmọ ọmọ Israẹli tí wọ́n lọ sí ilẹ̀ Ijipti, Jakọbu ati àwọn ọmọ rẹ̀: Reubẹni, àkọ́bí rẹ̀, ati àwọn ọmọ Reubẹni wọnyi: Hanoku, Palu, Hesironi, ati Karimi. Àwọn ọmọ ti Simeoni ni: Jemueli, Jamini, Ohadi, Jakini, Sohari, ati Ṣaulu, tí obinrin ará Kenaani bí fún un. Àwọn ọmọ ti Lefi ni: Geriṣoni, Kohati, ati Merari. Àwọn ọmọ ti Juda ni: Eri, Onani, Ṣela, Peresi, ati Sera, (ṣugbọn, Eri ati Onani ti kú ní ilẹ̀ Kenaani) àwọn ọmọ ti Peresi ni Hesironi ati Hamuli. Àwọn ọmọ ti Isakari ni: Tola, Pua, Jobu ati Ṣimironi. Àwọn ọmọ ti Sebuluni ni: Seredi, Eloni, ati Jaleeli. (Àwọn ni ọmọ tí Lea bí fún Jakọbu ní Padani-aramu ati Dina, ọmọ rẹ̀ obinrin.) Gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin jẹ́ mẹtalelọgbọn. Àwọn ọmọ ti Gadi ni: Sifioni, Hagi, Ṣuni, Esiboni, Eri, Arodu, ati Areli. Àwọn ọmọ ti Aṣeri ni: Imina, Iṣifa, Iṣifi, Beraya, ati Sera arabinrin wọn. Àwọn ọmọ ti Beraya ni Heberi, ati Malikieli. (Àwọn ni ọmọ tí Silipa bí fún Jakọbu. Silipa ni iranṣẹ tí Labani fún Lea ọmọ rẹ̀ obinrin, gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ́ mẹrindinlogun.) Àwọn ọmọ ti Rakẹli ni Josẹfu ati Bẹnjamini. Asenati, ọmọbinrin Pọtifera bí Manase ati Efuraimu fún Josẹfu ní ilẹ̀ Ijipti. Pọtifera ni babalóòṣà oriṣa Oni, ní Ijipti. Àwọn ọmọ ti Bẹnjamini ni: Bela, Bekeri, Aṣibeli, Gera, Naamani, Ehi, Roṣi, Mupimu, Hupimu, ati Aridi, (àwọn wọnyi ni ọmọ tí Rakẹli bí fún Jakọbu ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀. Gbogbo wọn jẹ́ mẹrinla). Ọmọ ti Dani ni Huṣimu. Àwọn ọmọ ti Nafutali ni Jaseeli, Guni, Jeseri, ati Ṣilemu. (Àwọn ọmọ tí Biliha bí fún Jakọbu ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ jẹ́ meje), Biliha ni iranṣẹbinrin tí Labani fún Rakẹli, ọmọ rẹ̀ obinrin. Gbogbo àwọn tí wọ́n bá Jakọbu lọ sí Ijipti, tí wọ́n jẹ́ ọmọ tabi ọmọ ọmọ rẹ̀ jẹ́ mẹrindinlaadọrin, láìka àwọn iyawo àwọn ọmọ rẹ̀. Àwọn ọmọ tí Josẹfu bí ní Ijipti jẹ́ meji. Gbogbo eniyan tí ó ti ìdílé Jakọbu jáde lọ sí Ijipti patapata wá jẹ́ aadọrin. Jakọbu rán Juda ṣáájú lọ sọ́dọ̀ Josẹfu pé kí Josẹfu wá pàdé òun ní Goṣeni, wọ́n sì wá sí ilẹ̀ Goṣeni. Josẹfu bọ́ sinu kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin rẹ̀, ó lọ pàdé Israẹli, baba rẹ̀ ní Goṣeni. Nígbà tí Josẹfu dé ọ̀dọ̀ baba rẹ̀, ó rọ̀ mọ́ ọn lọ́rùn, ó sì sọkún fún ìgbà pípẹ́. Israẹli bá wí fún Josẹfu, ó ní, “Níwọ̀n ìgbà tí mo ti fi ojú kàn ọ́ báyìí, tí mo sì rí i pé o wà láàyè, bí ikú bá tilẹ̀ wá dé, ó yá mi.” Josẹfu sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀ ati gbogbo ìdílé baba rẹ̀ pé òun óo lọ sọ fún Farao pé àwọn arakunrin òun ati ìdílé baba òun tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Kenaani ti dé sọ́dọ̀ òun. Ati pé darandaran ni wọ́n, ìtọ́jú ẹran ọ̀sìn ni iṣẹ́ wọn, wọ́n sì kó gbogbo agbo mààlúù ati agbo ewúrẹ́, ati ohun gbogbo tí wọ́n ní lọ́wọ́ wá. Ó ní nígbà tí Farao bá pè wọ́n, tí ó bá bi wọ́n léèrè pé irú iṣẹ́ wo ni wọ́n ń ṣe, kí wọ́n dá a lóhùn pé, ẹran ọ̀sìn ni àwọn ti ń tọ́jú láti ìgbà èwe àwọn títí di ìsinsìnyìí, ati àwọn ati àwọn baba àwọn, kí ó lè jẹ́ kí wọ́n máa gbé ilẹ̀ Goṣeni, nítorí pé ìríra patapata ni gbogbo darandaran jẹ́ fún àwọn ará Ijipti. Josẹfu bá wọlé lọ sọ fún Farao pé, “Baba mi ati àwọn arakunrin mi ti dé láti ilẹ̀ Kenaani, pẹlu gbogbo agbo ẹran ati agbo mààlúù wọn, ati ohun gbogbo tí wọ́n ní, wọ́n sì wà ní ilẹ̀ Goṣeni báyìí.” Ó mú marun-un ninu àwọn arakunrin rẹ̀, ó fi wọ́n han Farao. Farao bi àwọn arakunrin rẹ̀ léèrè irú iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe. Wọ́n dá Farao lóhùn pé, darandaran ni àwọn gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn. Wọ́n tún wí fún Farao pé, àwọn wá láti ṣe àtìpó ní ilẹ̀ rẹ̀ ni, nítorí pé ìyàn ńlá tí ó mú ní ilẹ̀ Kenaani kò jẹ́ kí koríko wà fún àwọn ẹran àwọn. Wọ́n ní àwọn wá bẹ Farao ni, pé kí ó jẹ́ kí àwọn máa gbé ilẹ̀ Goṣeni. Farao bá sọ fún Josẹfu pé, “Ọ̀dọ̀ rẹ ni baba rẹ ati àwọn arakunrin rẹ wá. Wo ilẹ̀ Ijipti láti òkè dé ilẹ̀, ibikíbi tí o bá rí i pé ó dára jùlọ ninu gbogbo ilẹ̀ náà ni kí o fi baba rẹ ati àwọn arakunrin rẹ sí. Jẹ́ kí wọ́n máa gbé ilẹ̀ Goṣeni, bí o bá sì mọ èyíkéyìí ninu wọn tí ó lè bojútó àwọn ẹran ọ̀sìn dáradára, fi ṣe alabojuto àwọn ẹran ọ̀sìn mi.” Josẹfu bá mú Jakọbu baba rẹ̀ wọlé láti fihan Farao, Jakọbu sì súre fún Farao. Farao bi Jakọbu pé, “Ẹni ọdún mélòó ni ọ́ báyìí?” Jakọbu dá a lóhùn pé, “Ọjọ́ orí mi jẹ́ aadoje (130) ọdún. Ọjọ́ orí mi kò tó nǹkan rárá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú mi ti rí ọpọlọpọ ibi. Ọjọ́ orí mi kò tíì dé ibìkan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti àwọn baba mi.” Jakọbu súre fún Farao ó sì jáde kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Josẹfu bá fi baba ati àwọn arakunrin rẹ̀ sí ibi tí ó dára jùlọ ní ilẹ̀ Ijipti, ninu ilẹ̀ Ramesesi, gẹ́gẹ́ bí Farao ti pa á láṣẹ. Josẹfu pèsè ohun jíjẹ fún baba ati àwọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo àwọn ìdílé baba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí iye eniyan tí olukuluku wọn ń bọ́. Ìyàn náà mú tóbẹ́ẹ̀ tí ìdààmú bá gbogbo ilẹ̀ Ijipti ati ilẹ̀ Kenaani nítorí pé kò sí oúnjẹ rárá ní ilẹ̀ Kenaani. Gbogbo owó tí àwọn ará ilẹ̀ Ijipti ati àwọn ará ilẹ̀ Kenaani ní patapata ni wọ́n kó tọ Josẹfu wá láti fi ra oúnjẹ. Josẹfu sì kó gbogbo owó náà lọ fún Farao. Nígbà tí kò sí owó mọ́ rárá ní ilẹ̀ Ijipti ati ilẹ̀ Kenaani, gbogbo àwọn ará Ijipti tọ Josẹfu lọ, wọ́n wí pé, “Fún wa ní oúnjẹ. Ǹjẹ́ o lè máa wò wá níran báyìí títí tí a óo fi kú? Kò sí owó lọ́wọ́ wa mọ́ rárá.” Josẹfu bá dá wọn lóhùn pé, “Bí kò bá sí owó lọ́wọ́ yín mọ́, ẹ kó àwọn ẹran ọ̀sìn yín wá, n óo sì fun yín ní oúnjẹ dípò wọn.” Wọ́n bá kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn tọ Josẹfu lọ, Josẹfu sì fún wọn ní oúnjẹ dípò àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, agbo ẹran wọn, agbo mààlúù wọn ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn. Ó fi àwọn ẹran ọ̀sìn wọn dí oúnjẹ fún wọn ní ọdún náà. Nígbà tí ọdún náà parí, wọ́n tún wá sọ́dọ̀ Josẹfu ní ọdún keji, wọ́n ní, “A kò jẹ́ purọ́ fún oluwa wa, pé kò sí owó lọ́wọ́ wa mọ́ rárá, gbogbo agbo ẹran wa sì ti di tìrẹ, a kò ní ohunkohun mọ́ àfi ara wa ati ilẹ̀ wa. Ǹjẹ́ o lè máa wò wá níran títí tí a óo fi kú, ati àwa, ati ilẹ̀ wa? Fi oúnjẹ ra àwa ati ilẹ̀ wa, a óo sì di ẹrú Farao. Fún wa ní irúgbìn, kí á lè wà láàyè, kí ilẹ̀ yìí má baà di ahoro.” Josẹfu bá ra gbogbo ilẹ̀ Ijipti fún Farao, nítorí pé gbogbo àwọn ará Ijipti ni wọ́n ta ilẹ̀ wọn, nítorí ìyàn náà dà wọ́n láàmú pupọ. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ilẹ̀ Ijipti ṣe di ti Farao, ó sì sọ àwọn eniyan náà di ẹrú rẹ̀ jákèjádò ilẹ̀ Ijipti. Àfi ilẹ̀ àwọn babalóòṣà nìkan ni kò rà, nítorí pé ó ní iye tí Farao máa ń fún wọn nígbàkúùgbà. Ohun tí Farao ń fún wọn yìí ni wọ́n sì fi ń jẹun. Ìdí nìyí tí kò jẹ́ kí wọ́n ta ilẹ̀ wọn. Josẹfu sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Àtẹ̀yin, àtilẹ̀ yín, láti òní lọ, mo ra gbogbo yín fún Farao. Irúgbìn nìyí, ẹ lọ gbìn ín sinu oko yín. Nígbà tí ẹ bá kórè, ẹ óo pín gbogbo ohun tí ẹ bá kórè sí ọ̀nà marun-un, ìpín kan jẹ́ ti Farao, ìpín mẹrin yòókù yóo jẹ́ tiyín. Ninu rẹ̀ ni ẹ óo ti mú irúgbìn, ati èyí tí ẹ óo máa jẹ, ẹ̀yin ati gbogbo ìdílé yín pẹlu àwọn ọmọ yín.” Wọ́n dáhùn pé, “Ìwọ ni o gbà wá lọ́wọ́ ikú, bí ó bá ti wù ọ́ bẹ́ẹ̀, a óo di ẹrú Farao.” Bẹ́ẹ̀ ni Josẹfu ṣe sọ ọ́ di òfin ní ilẹ̀ Ijipti, tí ó sì wà títí di òní olónìí pé ìdámárùn-ún gbogbo ìkórè oko jẹ́ ti Farao, ati pé ilẹ̀ àwọn babalóòṣà nìkan ni kì í ṣe ti Farao. Israẹli ń gbé ilẹ̀ Ijipti, ní Goṣeni, wọ́n sì ní ọpọlọpọ ohun ìní níbẹ̀, wọ́n bímọ lémọ, wọ́n sì pọ̀ sí i gidigidi. Ọdún mẹtadinlogun ni Jakọbu gbé sí i ní ilẹ̀ Ijipti, gbogbo ọdún tí ó gbé láyé sì jẹ́ ọdún mẹtadinlaadọjọ (147). Nígbà tí àkókò tí Jakọbu yóo kú súnmọ́ tòsí, ó pe Josẹfu ọmọ rẹ̀, ó wí fún un pé, “Wá, ti ọwọ́ rẹ bọ abẹ́ itan mi, kí o sì ṣèlérí pé o óo ṣe olóòótọ́ sí mi, o kò sì ní dà mí. Má ṣe sin òkú mi sí ilẹ̀ Ijipti, ṣugbọn gbé mi kúrò ní ilẹ̀ Ijipti kí o sì sin mí sí ibojì àwọn baba mi. Ibi tí wọ́n sin wọ́n sí ni mo fẹ́ kí o sin èmi náà sí.” Josẹfu dáhùn, ó ní, “Mo gbọ́, n óo ṣe bí o ti wí.” Jakọbu ní kí Josẹfu búra fún òun, Josẹfu sì búra fún un. Nígbà náà ni Jakọbu tẹríba lórí ibùsùn rẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n sọ fún Josẹfu pé ara baba rẹ̀ kò yá, Josẹfu bá mú àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji, Manase ati Efuraimu, lọ́wọ́ lọ bẹ baba rẹ̀ wò. Nígbà tí wọ́n sọ fún Jakọbu pé Josẹfu ọmọ rẹ̀ dé, ó ṣe ara gírí, ó jókòó lórí ibùsùn rẹ̀. Jakọbu sọ fún Josẹfu pé, “Ọlọrun Olodumare farahàn mí ní Lusi ní ilẹ̀ Kenaani, ó sì súre fún mi. Ó ní, ‘N óo fún ọ ní ọpọlọpọ ọmọ, n óo sì sọ ọ́ di ọpọlọpọ ẹ̀yà, ati pé àwọn ọmọ ọmọ rẹ ni n óo fi ilẹ̀ náà fún, yóo sì jẹ́ tiwọn títí ayé.’ “Tèmi ni àwọn ọmọkunrin mejeeji tí o bí ní ilẹ̀ Ijipti kí n tó dé, bí Reubẹni ati Simeoni ti jẹ́ tèmi, bẹ́ẹ̀ náà ni Manase ati Efuraimu jẹ́ tèmi. Àwọn ọmọ tí o bá tún bí lẹ́yìn wọn, ìwọ ni o ni wọ́n, ninu ogún tí ó bá kan Manase ati Efuraimu ni wọn yóo ti pín. Ìbànújẹ́ ni ó jẹ́ fún mi pé nígbà tí mò ń ti Padani-aramu bọ̀, Rakẹli kú lọ́nà, ní ilẹ̀ Kenaani, ibi tí ó dákẹ́ sí kò jìnnà pupọ sí Efurati. Lójú ọ̀nà Efurati náà ni mo sì sin ín sí.” (Efurati yìí ni wọ́n ń pè ní Bẹtilẹhẹmu.) Nígbà tí Israẹli rí àwọn ọmọ Josẹfu, ó bèèrè pé, “Àwọn wo nìyí?” Josẹfu dá baba rẹ̀ lóhùn, ó ní, “Àwọn ọmọ mi, tí Ọlọrun pèsè fún mi níhìn-ín ni wọ́n.” Jakọbu bá wí fún un pé, “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí wọ́n súnmọ́ mi kí n lè súre fún wọn.” Ogbó ti mú kí ojú Israẹli di bàìbàì ní àkókò yìí, kò sì ríran dáradára mọ́. Josẹfu bá kó wọn súnmọ́ baba rẹ̀, baba rẹ̀ dì mọ́ wọn, ó sì fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu. Ó wí fún Josẹfu pé, “N kò lérò pé mo tún lè fi ojú kàn ọ́ mọ́, ṣugbọn Ọlọrun mú kí ó ṣeéṣe fún mi láti rí àwọn ọmọ rẹ.” Josẹfu bá kó wọn kúrò lẹ́sẹ̀ baba rẹ̀, òun gan-an náà wá dojúbolẹ̀ níwájú baba rẹ̀. Ó fi ọwọ́ ọ̀tún mú Efuraimu, ó fà á súnmọ́ ẹ̀gbẹ́ ọwọ́ òsì baba rẹ̀, ó fi ọwọ́ òsì mú Manase, ó fà á súnmọ́ ẹ̀gbẹ́ ọwọ́ ọ̀tún baba rẹ̀. Ṣugbọn nígbà tí Israẹli na ọwọ́ rẹ̀ láti súre fún wọn, ó dábùú ọwọ́ rẹ̀ lórí ara wọn, ó gbé ọwọ́ ọ̀tún lé Efuraimu lórí, ó sì gbé ọwọ́ òsì lé Manase lórí, bẹ́ẹ̀ ni Efuraimu ni àbúrò, Manase sì ni àkọ́bí. Ó bá súre fún Josẹfu, ó ní, “Kí Ọlọrun tí Abrahamu ati Isaaki, baba mi, ń sìn bukun àwọn ọmọ wọnyi, kí Ọlọrun náà tí ó ti ń tọ́ mi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi títí di òní yìí bukun wọn, kí angẹli tí ó yọ mí ninu gbogbo ewu bukun wọn; kí ìrántí orúkọ mi, ati ti Abrahamu, ati ti Isaaki, àwọn baba mi, wà ní ìran wọn títí ayé, kí atọmọdọmọ wọn pọ̀ lórí ilẹ̀ ayé.” Nígbà tí Josẹfu rí i pé ọwọ́ ọ̀tún ni baba òun gbé lé Efuraimu lórí, kò dùn mọ́ ọn. Ó bá di ọwọ́ baba rẹ̀ mú láti gbé e kúrò lórí Efuraimu kí ó sì gbé e lórí Manase. Ó wí fún baba rẹ̀ pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, baba, eléyìí ni àkọ́bí, gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ lé e lórí.” Ṣugbọn baba rẹ̀ kọ̀, ó ní, “Mo mọ̀, ọmọ mi, mo mọ̀, òun náà yóo di eniyan, yóo sì di alágbára, ṣugbọn sibẹsibẹ àbúrò rẹ̀ yóo jù ú lọ, àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ yóo sì di ọpọlọpọ orílẹ̀ èdè.” Ó bá súre fún wọn ní ọjọ́ náà, ó ní, “Orúkọ yín ni Israẹli yóo fi máa súre fún eniyan, wọn yóo máa súre pé, ‘Kí Ọlọrun kẹ́ ọ bí ó ti kẹ́ Efuraimu ati Manase.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe fi Efuraimu ṣáájú Manase. Nígbà náà ni Israẹli sọ fún Josẹfu pé, “Àkókò ikú mi súnmọ́ etílé, ṣugbọn Ọlọrun yóo wà pẹlu rẹ, yóo sì mú ọ pada sí ilẹ̀ baba rẹ. Dípò kí n fún àwọn arakunrin rẹ ní Ṣekemu, tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ òkè, níbi tí mo jagun gbà lọ́wọ́ àwọn ará Amori, ìwọ ni mo fún.” Jakọbu ranṣẹ pe àwọn ọmọ rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ kó ara yín jọ kí n lè sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ si yín ní ọjọ́ iwájú fún yín. Ẹ péjọ kí ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, kí ẹ sì fetí sí ọ̀rọ̀ Israẹli, baba yín. Reubẹni, ìwọ ni àkọ́bí mi, agbára mi, ati àkọ́so èso agbára mi, ìwọ tí o ní ìgbéraga jùlọ, tí o sì lágbára jùlọ ninu àwọn ọmọ mi. Ìwọ tí o dàbí ìkún omi tí ń bì síwá sẹ́yìn, o kò ní jẹ́ olórí, nítorí pé o ti bá obinrin mi lòpọ̀, o sì ti sọ ibùsùn èmi baba rẹ di aláìmọ́. Simeoni ati Lefi jẹ́ arakunrin, ìlò ìkà ati ipá ni wọ́n ń lo idà wọn. Orí mi má jẹ́ kí n bá wọn pa ìmọ̀ pọ̀, ẹlẹ́dàá mi má sì jẹ́ kí n bá wọn kẹ́gbẹ́. Nítorí wọn a máa fi ibinu paniyan, wọn a sì máa ṣá akọ mààlúù lọ́gbẹ́ bí ohun ìdárayá. Ìfibú ni ibinu wọn, nítorí pé ó le, ati ìrúnú wọn, nítorí ìkà ni wọ́n. N óo pín wọn káàkiri ilẹ̀ Jakọbu, n óo sì fọ́n wọn ká ààrin àwọn eniyan Israẹli. Juda, àwọn arakunrin rẹ yóo máa yìn ọ́, apá rẹ yóo sì ká àwọn ọ̀tá rẹ; àwọn ọmọ baba rẹ yóo máa tẹríba fún ọ. Juda dàbí kinniun, tí ó bá pa ohun tí ó ń dọdẹ tán, a sì tún yan pada sinu ihò rẹ̀. Tí ó bá nà kalẹ̀, tí ó sì lúgọ, kò sí ẹni tí ó jẹ́ tọ́ ọ. Ọ̀pá àṣẹ ọba kì yóo kúrò ní ilé Juda, arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo sì máa jọba, títí tí yóo fi dé ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ni ín; gbogbo ìran eniyan ni yóo sì máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́. Yóo máa so ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mọ́ ìtàkùn àjàrà, yóo so àwọ́nsìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mọ́ ìtàkùn àjàrà dáradára, bẹ́ẹ̀ ni oje àjàrà ni yóo máa fi fọ ẹ̀wù rẹ̀. Ojú rẹ̀ yóo pọ́n fún àmutẹ́rùn ọtí waini, eyín rẹ̀ yóo sì funfun fún àmutẹ́rùn omi wàrà. “Sebuluni yóo máa gbé etí òkun, ọkọ̀ ojú omi rẹ̀ kò ní níye, Sidoni ni yóo jẹ́ ààlà rẹ̀. “Isakari dàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó lágbára tí ó dùbúlẹ̀ láàrin gàárì ẹrù rẹ̀. Ṣugbọn nígbà tí ó rí i pé ibi ìsinmi dára ati pé ilẹ̀ náà dára, ó tẹ́ ẹ̀yìn sílẹ̀ láti ru ẹrù, ó sì di ẹni tí wọn ń mú sìn bí ẹrú. Dani ni yóo máa ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli. Dani yóo dàbí ejò lójú ọ̀nà, ati bíi paramọ́lẹ̀ ní ẹ̀bá ọ̀nà, tí ń bu ẹṣin ní gìgísẹ̀ jẹ, kí ẹni tí ó gùn ún lè ṣubú sẹ́yìn. Mo dúró de ìgbàlà rẹ, Oluwa. Àwọn olè yóo máa kó Gadi lẹ́rù, ṣugbọn bí wọ́n ti ń kó o, bẹ́ẹ̀ ni yóo sì máa gbà á pada. Aṣeri yóo máa rí oúnjẹ dáradára mú jáde ninu oko rẹ̀, oúnjẹ ọlọ́lá ni yóo máa ti inú oko rẹ̀ jáde. Nafutali dàbí àgbọ̀nrín tí ń sáré káàkiri, tí ó sì ní àwọn ọmọ tí ó lẹ́wà. Josẹfu dàbí igi eléso tí ó wà lẹ́bàá odò, àwọn ẹ̀ka rẹ̀ nà mọ́ ara ògiri. Àwọn tafàtafà gbógun tì í kíkankíkan, wọ́n ń ta á lọ́fà, wọ́n sì ń dà á láàmú gidigidi, sibẹsibẹ ọrùn rẹ̀ kò mì, apá rẹ̀ sì ń lágbára sí i. Agbára Ọlọrun Jakọbu ni ó fún apá rẹ̀ ní okun, (ní orúkọ Olùṣọ́-aguntan náà, tí í ṣe Àpáta ààbò Israẹli), Ọlọrun baba rẹ yóo ràn ọ́ lọ́wọ́. Ọlọrun Olodumare yóo rọ òjò ibukun sórí rẹ láti òkè ọ̀run wá, yóo sì fún ọ ní ibukun omi tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀, ati ọpọlọpọ ọmọ ati ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn. Ibukun àwọn baba rẹ ju ti àwọn òkè ayérayé lọ, kí ibukun àwọn òkè ayérayé wá sórí Josẹfu, ẹni tí wọ́n yà ní ipá lọ́dọ̀ àwọn arakunrin rẹ̀. “Bẹnjamini dàbí ìkookò tí ebi ń pa, a máa pa ohun ọdẹ rẹ̀ ní òwúrọ̀, ati ní àṣáálẹ́ a máa pín ìkógun rẹ̀.” Àwọn ẹ̀yà Israẹli mejeejila ni a ti dárúkọ yìí, ati ohun tí baba wọn wí nígbà tí ó súre fún wọn. Ó súre tí ó tọ́ sí olukuluku fún un. Jakọbu kìlọ̀ fún wọn, ó ní, “Mo ṣetán, mò ń re ibi àgbà á rè, inú ibojì tí wọ́n sin àwọn baba mi sí, ninu ihò òkúta tí ó wà ninu ilẹ̀ Efuroni, ará Hiti, ni kí ẹ sin mí sí. Ihò òkúta yìí wà ninu pápá ní Makipela, ní ìhà ìlà oòrùn Mamure ní ilẹ̀ Kenaani. Lọ́wọ́ Efuroni ará Hiti ni Abrahamu ti rà á pọ̀ mọ́ ilẹ̀ náà, kí ó lè rí ibi fi ṣe itẹ́ òkú. Níbẹ̀ ni wọ́n sin Abrahamu ati Sara aya rẹ̀ sí, níbẹ̀ náà ni wọ́n sin Isaaki sí ati Rebeka aya rẹ̀, níbẹ̀ ni èmi náà sì sin Lea sí. Lọ́wọ́ àwọn ará Hiti ni wọ́n ti ra ilẹ̀ náà ati ihò òkúta tí ó wà ninu rẹ̀. Níbẹ̀ ni kí ẹ sin mí sí.” Nígbà tí Jakọbu parí ìkìlọ̀ tí ó ń ṣe fún àwọn ọmọ rẹ̀, ó ká ẹsẹ̀ rẹ̀ pada sí orí ibùsùn rẹ̀, ó dùbúlẹ̀, lẹ́yìn náà ó mí kanlẹ̀, ó sì re ibi tí àgbà á rè. Josẹfu dojúbo òkú baba rẹ̀ lójú, ó sọkún, ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu. Lẹ́yìn náà, Josẹfu pàṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí wọn ń ṣiṣẹ́ ìṣègùn pé kí wọ́n fi òògùn tí wọ́n fi máa ń tọ́jú òkú, tí kì í fíí bàjẹ́, tọ́jú òkú baba òun. Wọ́n fi òògùn yìí tọ́jú òkú Jakọbu. Ogoji ọjọ́ gbáko ni àwọn oníṣègùn máa fi ń tọ́jú irú òkú bẹ́ẹ̀. Àwọn ará Ijipti sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ fún aadọrin ọjọ́. Nígbà tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ rẹ̀ parí, Josẹfu sọ fún àwọn ará ilé Farao pé, “Ẹ jọ̀wọ́, bí inú yín bá dùn sí mi, ẹ bá mi sọ fún Farao pé, baba mi mú mi búra nígbà tí àtikú rẹ̀ kù sí dẹ̀dẹ̀, pé, ‘Nígbà tí mo bá kú, ninu ibojì tí mo gbẹ́ fún ara mi ní ilẹ̀ Kenaani, ni kí ẹ sin mí sí.’ Nítorí náà, kí Farao jọ̀wọ́, fún mi láàyè kí n lọ sin òkú baba mi, n óo sì tún pada wá.” Farao dáhùn, ó ní, “Lọ sin òkú baba rẹ gẹ́gẹ́ bí o ti búra fún un.” Josẹfu lọ sin òkú baba rẹ̀, gbogbo àwọn iranṣẹ Farao sì bá a lọ, ati gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà ààfin ọba, ati gbogbo àwọn àgbààgbà ìlú Ijipti, ati gbogbo ìdílé Josẹfu àwọn arakunrin rẹ̀ ati ìdílé baba rẹ̀, àfi àwọn ọmọde, àwọn agbo ẹran, ati àwọn mààlúù nìkan ni ó kù sí ilẹ̀ Goṣeni. Kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin bá a lọ pẹlu, àwọn eniyan náà pọ̀ lọpọlọpọ. Nígbà tí wọ́n dé ibi ìpakà Atadi, níwájú Jọdani, wọ́n pohùnréré ẹkún, Josẹfu sì ṣọ̀fọ̀ baba rẹ̀ fún ọjọ́ meje. Nígbà tí àwọn ará Kenaani tí wọn ń gbé ibẹ̀ rí i bí wọ́n ti ń ṣọ̀fọ̀ ní ibi ìpakà náà, wọ́n wí pé, “Òkú yìí mà kúkú dun àwọn ará Ijipti o!” Nítorí náà, wọ́n sọ ibẹ̀ ní Abeli Misiraimu, ó wà ní apá ìlà oòrùn odò Jọdani. Àwọn ọmọ Jakọbu sin òkú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti pa á láṣẹ fún wọn. Wọ́n gbé òkú rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Kenaani, wọ́n sì sin ín sinu ihò òkúta tí ó wà ninu oko Makipela, ní ìhà ìlà oòrùn Mamure, tí Abrahamu rà mọ́ ilẹ̀ tí ó rà lọ́wọ́ Efuroni ará Hiti láti fi ṣe itẹ́ òkú. Nígbà tí Josẹfu sin òkú baba rẹ̀ tán, ó pada lọ sí ilẹ̀ Ijipti pẹlu àwọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo àwọn tí wọ́n bá a lọ. Nígbà tí àwọn arakunrin Josẹfu rí i pé baba àwọn ti kú, wọ́n ní, “Ó ṣeéṣe kí Josẹfu kórìíra wa, kí ó sì gbẹ̀san gbogbo ibi tí a ti ṣe sí i.” Wọ́n bá ranṣẹ sí Josẹfu pé, “Baba rẹ ti fi àṣẹ yìí lélẹ̀ kí ó tó kú pé, ‘Ẹ sọ fún Josẹfu pé, dárí àṣìṣe ati ẹ̀ṣẹ̀ àwọn arakunrin rẹ jì wọ́n, nítorí wọ́n ṣe ibi sí ọ.’ ” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀ ẹ́ pé, “Jọ̀wọ́, dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn iranṣẹ Ọlọrun baba rẹ jì wọ́n.” Nígbà tí Josẹfu gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó bú sẹ́kún. Àwọn arakunrin rẹ̀ náà sì wá, wọ́n wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n ní, “Wò ó, a di ẹrú rẹ.” Ṣugbọn Josẹfu wí fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù, èmi kì í ṣe Ọlọrun. Ní tiyín, ẹ gbèrò ibi sí mi, ṣugbọn Ọlọrun yí i pada sí rere, kí ó lè dá ẹ̀mí ọpọlọpọ eniyan tí wọ́n wà láàyè lónìí sí. Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù, n óo máa tọ́jú ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín.” Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe sọ̀rọ̀ ìtùnú fún wọn, tí ó sì dá wọn lọ́kànle. Josẹfu sì ń gbé ilẹ̀ Ijipti, òun ati ìdílé baba rẹ̀, ó gbé aadọfa (110) ọdún láyé. Josẹfu rí ìran kẹta ninu àwọn ọmọ Efuraimu. Àwọn ọmọ tí Makiri ọmọ Manase bí, ọwọ́ Josẹfu ni ó bí wọn sí pẹlu. Josẹfu sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀ pé, “Àtikú mi kù sí dẹ̀dẹ̀, ṣugbọn Ọlọrun yóo máa tọ́jú yín, yóo sì mu yín jáde kúrò ní ilẹ̀ yìí, lọ sí ilẹ̀ tí ó ṣèlérí fún Abrahamu ati Isaaki ati Jakọbu.” Josẹfu sì mú kí àwọn ọmọ Israẹli búra fún un pé, nígbà tí Ọlọrun bá mú wọn pada sí ilẹ̀ Kenaani, wọn yóo kó egungun òun lọ́wọ́ lọ. Josẹfu kú nígbà tí ó di ẹni aadọfa (110) ọdún. Wọ́n fi òògùn tọ́jú òkú rẹ̀ kí ó má baà bàjẹ́, wọ́n sì tẹ́ ẹ sinu pósí ní ilẹ̀ Ijipti. Orúkọ àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n bá Jakọbu wá sí Ijipti nìwọ̀nyí, olukuluku pẹlu ìdílé rẹ̀: Reubẹni, Simeoni, Lefi, Juda, Isakari, Sebuluni, Bẹnjamini, Dani, Nafutali, Gadi ati Aṣeri. Gbogbo àwọn ọmọ ati àwọn ọmọ ọmọ Jakọbu jẹ́ aadọrin, Josẹfu ti wà ní Ijipti ní tirẹ̀. Nígbà tí ó yá, Josẹfu kú, gbogbo àwọn arakunrin rẹ̀ náà kú ní ọ̀kọ̀ọ̀kan títí tí gbogbo ìran náà fi kú tán. Ṣugbọn àwọn arọmọdọmọ Israẹli pọ̀ sí i, wọ́n di alágbára gidigidi, wọ́n sì pọ̀ káàkiri ní ilẹ̀ Ijipti. Nígbà tí ó yá, ọba titun kan tí kò mọ Josẹfu gorí oyè, ní ilẹ̀ Ijipti. Ọba yìí sọ fún àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ẹ wò bí àwọn ọmọ Israẹli wọnyi ti pọ̀ tó, tí wọ́n sì lágbára jù wá lọ. Ẹ jẹ́ kí á fi ọgbọ́n bá wọn lò, nítorí bí wọ́n bá ń pọ̀ lọ báyìí, bí ogun bá bẹ́ sílẹ̀, wọn yóo darapọ̀ mọ́ àwọn ọ̀tá wa láti bá wa jà, wọn yóo sì sá kúrò ní ilẹ̀ yìí.” Nítorí náà, wọ́n yan àwọn akóniṣiṣẹ́ láti ni wọ́n lára pẹlu iṣẹ́ àṣekára. Wọ́n lò wọ́n láti kọ́ ìlú Pitomi ati Ramesesi tíí ṣe àwọn ìlú ìṣúra fún Farao. Ṣugbọn bí wọ́n ti ń da àwọn ọmọ Israẹli láàmú tó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń pọ̀ sí i, tí wọ́n sì ń tàn kálẹ̀. Ẹ̀rù àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí ba àwọn ará Ijipti. Nítorí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi iṣẹ́ àṣekára ni àwọn ọmọ Israẹli lára, wọ́n sì ń fòòró ẹ̀mí wọn pẹlu oríṣìíríṣìí iṣẹ́ líle. Wọ́n ń po yẹ̀ẹ̀pẹ̀, wọ́n ń mọ bíríkì, wọ́n ń ṣiṣẹ́ ninu oko. Pẹlu ìnira ni wọ́n sì ń ṣe gbogbo iṣẹ́ tí wọn ń ṣe. Nígbà tí ó yá, ọba Ijipti pe àwọn obinrin Heberu tí wọ́n ń gbẹ̀bí, tí orúkọ wọn ń jẹ́ Ṣifira ati Pua, ó sọ fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ bá ń gbẹ̀bí fún àwọn obinrin Israẹli, tí ẹ sì rí i pé ọmọ tí wọ́n fẹ́ bí jẹ́ ọkunrin, ẹ pa á, ṣugbọn bí ó bá jẹ́ obinrin ni, ẹ dá a sí.” Ṣugbọn àwọn agbẹ̀bí náà bẹ̀rù Ọlọrun; wọn kò tẹ̀lé àṣẹ tí ọba Ijipti pa fún wọn, pé kí wọn máa pa àwọn ọmọkunrin tí àwọn obinrin Heberu bá ń bí. Ọba Ijipti bá pe àwọn agbẹ̀bí náà, ó bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń dá àwọn ọmọkunrin tí àwọn Heberu bí sí?” Wọ́n dá Farao lóhùn pé, “Àwọn obinrin Heberu yàtọ̀ sí àwọn obinrin Ijipti. Wọ́n lágbára, wọn a sì ti máa bímọ kí á tó dé ọ̀dọ̀ wọn.” Nítorí náà, Ọlọrun ṣe àwọn agbẹ̀bí náà dáradára; àwọn eniyan Israẹli ń pọ̀ sí i, wọ́n sì ń lágbára sí i. Nítorí pé àwọn agbẹ̀bí náà bẹ̀rù Ọlọrun, ìdílé tiwọn náà pọ̀ síi. Farao bá pàṣẹ fún gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Gbogbo ọmọkunrin tí àwọn Heberu bá bí, ẹ máa gbé wọn sọ sinu odò Naili, ṣugbọn kí ẹ dá àwọn ọmọbinrin wọn sí.” Ní àkókò náà, ọkunrin kan láti inú ẹ̀yà Lefi fẹ́ obinrin kan tí òun náà jẹ́ ẹ̀yà Lefi. Obinrin náà lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan. Nígbà tí ó rí i pé ọmọ náà jẹ́ arẹwà, ó gbé e pamọ́ fún oṣù mẹta. Nígbà tí kò lè gbé e pamọ́ mọ́, ó fi koríko kan tí ó dàbí èèsún ṣe apẹ̀rẹ̀ kan, ó fi oje igi ati ọ̀dà ilẹ̀ rẹ́ ẹ, ó gbé ọmọ náà sinu rẹ̀, ó sì gbé apẹ̀rẹ̀ náà sí ààrin koríko lẹ́bàá odò. Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obinrin dúró ní òkèèrè, ó ń wo ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí i. Láìpẹ́, ọmọbinrin Farao lọ wẹ̀ ní odò náà, àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ sì ń rìn káàkiri etídò. Ó rí apẹ̀rẹ̀ náà láàrin koríko, ó bá rán iranṣẹbinrin rẹ̀ lọ gbé apẹ̀rẹ̀ náà. Nígbà tí ó ṣí i, ó rí ọmọ kan ninu rẹ̀, ọmọ náà ń sọkún. Àánú ṣe é, ó wí pé, “Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Heberu nìyí.” Ẹ̀gbọ́n ọmọ náà bá bi ọmọbinrin Farao pé, “Ṣé kí n lọ pe olùtọ́jú kan wá lára àwọn obinrin Heberu, kí ó máa bá ọ tọ́jú ọmọ yìí?” Ọmọbinrin Farao dá a lóhùn pé, “Lọ pè é wá.” Ọmọbinrin náà bá yára lọ pe ìyá ọmọ náà. Ọmọbinrin Farao sọ fún ìyá ọmọ náà pé, “Gbé ọmọ yìí lọ, kí o máa bá mi tọ́jú rẹ̀, n óo sì san owó àgbàtọ́ rẹ̀ fún ọ.” Bẹ́ẹ̀ ni obinrin náà ṣe gba ọmọ, ó sì ń tọ́jú rẹ̀. Nígbà tí ọmọ náà dàgbà, ó gbé e pada fún ọmọbinrin Farao, ó sì fi ṣe ọmọ, ó sọ ọ́ ní Mose, ó wí pé, “Nítorí pé láti inú omi ni mo ti fà á jáde.” Nígbà tí Mose dàgbà, ní ọjọ́ kan, ó jáde lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀, ó sì rí i bí ìyà tí ń jẹ wọ́n. Ó rí i tí ará Ijipti kan ń lu ọ̀kan ninu àwọn Heberu, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Nígbà tí ó wo ọ̀tún, tí ó wo òsì, tí kò rí ẹnìkankan, ó lu ará Ijipti náà pa, ó sì bò ó mọ́ inú yanrìn. Nígbà tí ó tún jáde lọ ní ọjọ́ keji, ó rí i tí àwọn Heberu meji ń jà; ó bá bi ẹni tí ó jẹ̀bi pé, “Kí ló dé tí o fi ń lu ẹnìkejì rẹ?” Ọkunrin náà dáhùn pé, “Ta ló fi ọ́ jẹ olórí ati onídàájọ́ wa? Ṣé o fẹ́ pa èmi náà bí o ti pa ará Ijipti níjelòó ni?” Ẹ̀rù ba Mose, ó sì rò ó lọ́kàn rẹ̀ pé, “Láìsí àní àní, ọ̀rọ̀ yìí ti di mímọ̀.” Nígbà tí Farao gbọ́, ó ń wá ọ̀nà àtipa Mose. Ṣugbọn Mose sálọ mọ́ ọn lọ́wọ́, ó lọ sí ilẹ̀ Midiani, ó sì jókòó lẹ́bàá kànga kan. Àwọn ọmọbinrin meje kan wá pọn omi, wọ́n jẹ́ ọmọ Jẹtiro, alufaa ìlú Midiani. Wọ́n pọn omi kún ọpọ́n ìmumi àwọn ẹran, láti fún àwọn agbo ẹran baba wọn ní omi mu. Nígbà tí àwọn olùṣọ́-aguntan dé, wọ́n lé àwọn ọmọbinrin meje náà sẹ́yìn; ṣugbọn Mose dìde, ó ran àwọn ọmọbinrin náà lọ́wọ́, ó sì fún àwọn ẹran wọn ní omi mu. Nígbà tí wọ́n pada dé ọ̀dọ̀ Reueli, baba wọn, ó bi wọ́n pé, “Ó ṣe ya yín tó báyìí lónìí?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ará Ijipti kan ni ó gbà wá kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn olùṣọ́-aguntan náà, ó tilẹ̀ tún bá wa pọn omi fún agbo ẹran wa.” Reueli bá bi àwọn ọmọ rẹ̀ léèrè pé, “Níbo ni ará Ijipti ọ̀hún wà? Kí ló dé tí ẹ fi sílẹ̀? Ẹ lọ pè é wọlé, kí ó wá jẹun.” Mose gbà láti máa gbé ọ̀dọ̀ ọkunrin náà, ó bá fún un ní Sipora, ọ̀kan ninu àwọn ọmọbinrin rẹ̀ láti fi ṣe aya. Ó bí ọmọkunrin kan, ó sì sọ ọmọ náà ní Geriṣomu, ó wí pé, “Mo jẹ́ àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì.” Lẹ́yìn ọpọlọpọ ọdún, ọba Ijipti kú, àwọn ọmọ Israẹli sì ń kérora ní oko ẹrú tí wọ́n wà, wọ́n kígbe fún ìrànlọ́wọ́. Igbe tí wọn ń ké ní oko ẹrú sì gòkè tọ OLUWA lọ. Ọlọrun gbọ́ ìkérora wọn, ó sì ranti majẹmu tí ó bá Abrahamu, ati Isaaki, ati Jakọbu dá. Ọlọrun bojú wo àwọn eniyan Israẹli, ó sì rí irú ipò tí wọ́n wà. Ní ọjọ́ kan, Mose ń ṣọ́ agbo ẹran Jẹtiro, baba iyawo rẹ̀, tíí ṣe alufaa ìlú Midiani. Ó da agbo ẹran náà lọ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn aṣálẹ̀, títí tí ó fi dé òkè Horebu ní Sinai, tíí ṣe òkè Ọlọrun. Angẹli OLUWA farahàn án ninu ahọ́n iná láàrin ìgbẹ́; bí ó ti wò ó, ó rí i pé iná ń jó nítòótọ́, ṣugbọn igbó náà kò jóná. Mose bá wí ninu ara rẹ̀ pé, “N óo súnmọ́ kinní yìí, mo fẹ́ wo ohun ìyanu yìí, ìdí tí iná fi ń jó tí igbó kò sì fi jóná.” Nígbà tí Ọlọrun rí i pé ó súnmọ́ ọn láti wo ohun ìyanu náà, Ọlọrun pè é láti inú igbó náà, ó ní, “Mose! Mose!” Mose dáhùn pé, “Èmi nìyí.” Ọlọrun ní, “Má ṣe súnmọ́ tòsí ibí, bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ, nítorí pé, ilẹ̀ tí o dúró sí yìí, ilẹ̀ mímọ́ ni.” Ọlọrun tún fi kún un pé, “Èmi ni Ọlọrun baba rẹ, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu.” Mose bá bo ojú rẹ̀ nítorí pé ẹ̀rù ń bà á láti wo Ọlọrun. Lẹ́yìn náà OLUWA dáhùn pé, “Mo ti rí ìpọ́njú àwọn eniyan mi tí wọ́n wà ní Ijipti, mo sì ti gbọ́ igbe wọn, nítorí ìnilára àwọn tí ń kó wọn ṣiṣẹ́, mo mọ irú ìyà tí wọn ń jẹ, mo sì ti sọ̀kalẹ̀ wá láti wá gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti, ati láti kó wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ náà lọ sí ilẹ̀ kan tí ó dára, tí ó sì tẹ́jú, ilẹ̀ tí ó lẹ́tù lójú tí ó kún fún wàrà ati oyin, àní, ilẹ̀ àwọn ará Kenaani, ati ti àwọn ará Hiti, ati ti àwọn ará Perisi, ati ti àwọn ará Hifi ati ti àwọn ará Jebusi. Igbe àwọn eniyan Israẹli ti gòkè tọ̀ mí wá, mo sì ti rí bí àwọn ará Ijipti ṣe ń ni wọ́n lára. Wá, n óo rán ọ sí Farao, kí o lè lọ kó àwọn eniyan mi, àwọn ọmọ Israẹli, jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.” Ṣugbọn Mose dá Ọlọrun lóhùn pé, “Ta ni mo jẹ́, tí n óo fi wá tọ Farao lọ pé mo fẹ́ kó àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní ilẹ̀ Ijipti?” Ọlọrun bá dá a lóhùn pé, “N óo wà pẹlu rẹ, ohun tí yóo sì jẹ́ àmì fún ọ, pé èmi ni mo rán ọ ni pé, nígbà tí o bá ti kó àwọn eniyan náà kúrò ní Ijipti, ẹ óo sin Ọlọrun ní orí òkè yìí.” Mose tún bi Ọlọrun pé, “Bí mo bá dé ọ̀dọ̀ àwọn eniyan Israẹli, tí mo sì wí fún wọn pé, ‘Ọlọrun àwọn baba yín ni ó rán mi sí i yín,’ bí wọ́n bá wá bi mí pé ‘Kí ni orúkọ rẹ̀?’ Kí ni kí n wí fún wọn?” Ọlọrun dá Mose lóhùn pé, “ÈMI NI ẸNI TÍ MO JẸ́. Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘ÈMI NI ni ó rán mi sí yín.’ ” Ọlọrun tún fi kún un fún Mose pé kí ó sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu, ni ó rán òun sí wọn. Ó ní orúkọ òun nìyí títí ayérayé, orúkọ yìí ni wọn óo sì máa fi ranti òun láti ìrandíran. Ó ní, “Lọ kó gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli jọ, kí o sì sọ fún wọn pé, èmi OLUWA, Ọlọrun àwọn baba yín, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu, ni ó farahàn ọ́, ati pé, mo ti ń ṣàkíyèsí wọn, mo ti rí ohun tí àwọn ará Ijipti ti ṣe sí wọn. Mo ṣèlérí pé n óo yọ wọ́n kúrò ninu ìpọ́njú Ijipti. N óo kó wọn lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kenaani, ati ti àwọn ará Hiti, ati ti àwọn ará Amori, ati ti àwọn ará Perisi ati ti àwọn ará Hifi, ati ti àwọn ará Jebusi, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin. “Wọn yóo gbọ́rọ̀ sí ọ lẹ́nu, ìwọ ati àwọn àgbààgbà Israẹli yóo tọ ọba Ijipti lọ, ẹ óo sì wí fún un pé, ‘OLUWA Ọlọrun àwọn Heberu ti wá bá wa, jọ̀wọ́, jẹ́ kí á lọ sinu aṣálẹ̀, ní ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ mẹta, kí á lè rúbọ sí OLUWA, Ọlọrun wa.’ Mo mọ̀ pé ọba Ijipti kò ní jẹ́ kí ẹ lọ rárá, àfi bí mo bá fi ọwọ́ líle mú un. Nítorí náà n óo lo agbára mi láti fi jẹ Ijipti níyà, ń óo sì ṣe iṣẹ́ ìyanu níbẹ̀, nígbà náà ni yóo tó gbà pé kí ẹ máa lọ. “N óo jẹ́ kí àwọn eniyan wọnyi rí ojurere àwọn ará Ijipti, nígbà tí ẹ bá ń lọ, ẹ kò ní lọ lọ́wọ́ òfo, olukuluku obinrin yóo lọ sí ọ̀dọ̀ aládùúgbò rẹ̀ tí ó jẹ́ ará Ijipti ati àwọn àlejò tí wọ́n wọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀, yóo tọrọ aṣọ ati ohun ọ̀ṣọ́ wúrà ati ti fadaka, ẹ óo sì fi wọ àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo sì ṣe gba gbogbo ìṣúra àwọn ará Ijipti lọ́wọ́ wọn.” Mose dáhùn pé, “Wọn kò ní gbà mí gbọ́, wọn kò tilẹ̀ ní fetí sí ọ̀rọ̀ mi, wọn yóo wí pé, OLUWA kò farahàn mí.” OLUWA bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ló wà ní ọwọ́ rẹ yìí?” Ó dáhùn pé, “Ọ̀pá ni.” OLUWA ní, “Sọ ọ́ sílẹ̀.” Mose bá sọ ọ́ sílẹ̀, ọ̀pá náà sì di ejò, Mose bá sá sẹ́yìn. Ṣugbọn OLUWA sọ fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ, kí o mú un ní ìrù.” Mose nawọ́ mú un, ejò náà sì pada di ọ̀pá ní ọwọ́ rẹ̀. OLUWA wí pé, “Èyí yóo mú kí wọ́n gbàgbọ́ pé OLUWA, Ọlọrun àwọn baba wọn, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu ni ó farahàn ọ́.” OLUWA tún wí fún un pé, “Ti ọwọ́ rẹ bọ abíyá.” Mose sì ti ọwọ́ bọ abíyá. Nígbà tí ó yọ ọ́ jáde, ọwọ́ rẹ̀ dẹ́tẹ̀, ó sì funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Ọlọrun tún ní, “Ti ọwọ́ rẹ bọ abíyá pada.” Mose sì ti ọwọ́ bọ abíyá rẹ̀ pada; nígbà tí ó yọ ọ́ jáde, ọwọ́ rẹ̀ pada sí bí ó ti wà tẹ́lẹ̀. Ọlọrun ní, “Bí wọn kò bá fẹ́ gbà ọ́ gbọ́, tabi bí wọn kò bá náání àmì ti àkọ́kọ́, ó ṣeéṣe kí wọ́n gba àmì keji yìí gbọ́. Bí wọn kò bá gba àwọn àmì mejeeji wọnyi gbọ́, tí wọ́n sì kọ̀, tí wọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, lọ bu omi díẹ̀ ninu odò Naili kí o sì dà á sí orí ìyàngbẹ ilẹ̀; omi náà yóo di ẹ̀jẹ̀ bí o bá ti dà á sí orí ìyàngbẹ ilẹ̀.” Ṣugbọn Mose wí fún OLUWA pé, “OLUWA mi, n kò lè sọ̀rọ̀ dáradára kí o tó bá mi sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ náà sì ni lẹ́yìn tí o bá èmi iranṣẹ rẹ sọ̀rọ̀ tán, nítorí pé akólòlò ni mí.” OLUWA dá a lóhùn pé, “Ta ló dá ẹnu eniyan? Ta ni í mú kí eniyan ya odi, tabi kí ó ya adití, tabi kí ó ríran, tabi kí ó ya afọ́jú? Ṣebí èmi OLUWA ni. Nítorí náà, lọ, n óo sì wà pẹlu rẹ, n óo sì máa kọ́ ọ ní ohun tí o óo sọ.” Ṣugbọn Mose tún ní, “OLUWA mi, mo bẹ̀ ọ́, rán ẹlòmíràn.” Inú bí OLUWA sí Mose, ó ní, “Ṣebí Aaroni, ọmọ Lefi, arakunrin rẹ wà níbẹ̀? Mo mọ̀ pé òun lè sọ̀rọ̀ dáradára; ó ń bọ̀ wá pàdé rẹ, nígbà tí ó bá rí ọ, inú rẹ̀ yóo dùn gidigidi. O óo máa bá a sọ̀rọ̀, o óo sì fi ọ̀rọ̀ sí i lẹ́nu. N óo gbàkóso ẹnu rẹ ati ẹnu rẹ̀; n óo sì kọ yín ní ohun tí ẹ óo ṣe. Òun ni yóo máa bá ọ bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀, yóo jẹ́ ẹnu fún ọ, o óo sì dàbí Ọlọrun fún un. Mú ọ̀pá yìí lọ́wọ́, òun ni o óo máa fi ṣe iṣẹ́ ìyanu.” Mose pada lọ sí ọ̀dọ̀ Jẹtiro, baba iyawo rẹ̀, ó sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n pada lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn eniyan mi ní Ijipti, kí n lọ wò ó bóyá wọ́n wà láàyè.” Jẹtiro dá Mose lóhùn pé, “Máa lọ ní alaafia.” OLUWA sọ fún Mose ní Midiani pé, “Pada lọ sí Ijipti, nítorí pé gbogbo àwọn tí wọn ń lépa ẹ̀mí rẹ ti kú tán.” Mose bá gbé iyawo rẹ̀ ati àwọn ọmọkunrin rẹ̀ gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó pada lọ sí ilẹ̀ Ijipti, tòun ti ọ̀pá Ọlọrun ní ọwọ́ rẹ̀. OLUWA sọ fún Mose pé, “Nígbà tí o bá pada dé Ijipti, o gbọdọ̀ ṣe gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí mo fún ọ lágbára láti ṣe níwájú Farao, ṣugbọn n ó mú kí ọkàn rẹ̀ le, kò sì ní jẹ́ kí àwọn eniyan Israẹli lọ. O óo wí fún un pé, Èmi, OLUWA wí pé, ‘Israẹli ni àkọ́bí mi ọkunrin. Nítorí náà, jẹ́ kí ọmọ mi lọ, kí ó lè sìn mí. Bí o bá kọ̀, tí o kò jẹ́ kí ó lọ, pípa ni n óo pa àkọ́bí rẹ ọkunrin.’ ” Nígbà tí wọ́n dé ilé èrò kan ní ojú ọ̀nà Ijipti, OLUWA pàdé Mose, ó sì fẹ́ pa á. Sipora bá mú akọ òkúta pẹlẹbẹ tí ó mú, ó fi kọ ilà abẹ́ fún ọmọ rẹ̀, ó sì fi awọ tí ó gé kúrò kan ẹsẹ̀ Mose, ó wí fún Mose pé, “Ọkọ tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ gba kí á ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ni ọ́.” OLUWA bá fi Mose sílẹ̀, kò pa á mọ́. Nítorí àṣà ilà abẹ́ kíkọ náà ni Sipora ṣe wí pé, ọkọ tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ gba kí á ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ni Mose. OLUWA wí fún Aaroni pé, “Jáde lọ sinu aṣálẹ̀, kí o lọ pàdé Mose.” Ó jáde lọ, ó pàdé rẹ̀ ní òkè Ọlọrun, ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu. Mose sọ gbogbo iṣẹ́ tí OLUWA rán an fún un, ati gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí OLUWA pa láṣẹ pé kí ó ṣe. Mose ati Aaroni bá lọ sí Ijipti, wọ́n kó gbogbo àgbààgbà àwọn eniyan Israẹli jọ. Aaroni sọ gbogbo ohun tí OLUWA sọ fún Mose fún wọn, ó sì ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu náà lójú gbogbo àwọn àgbààgbà náà. Àwọn eniyan náà gba ọ̀rọ̀ wọn gbọ́; nígbà tí wọ́n gbọ́ pé OLUWA wá bẹ àwọn eniyan Israẹli wò, ati pé ó ti rí ìpọ́njú wọn, wọ́n tẹríba, wọ́n sì sin OLUWA. Lẹ́yìn náà, Mose ati Aaroni lọ sọ́dọ̀ Farao, wọ́n sọ fún un pé, “OLUWA, Ọlọrun Israẹli sọ pé, ‘Jẹ́ kí àwọn eniyan mi lọ, kí wọ́n lè lọ ṣe àjọ̀dún kan fún mi ninu aṣálẹ̀.’ ” Ṣugbọn Farao dá wọn lóhùn pé, “Ta ni OLUWA yìí tí n óo fi fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀, kí n sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli lọ? N kò mọ OLUWA ọ̀hún, ati pé n kò tilẹ̀ lè gbà rárá pé kí àwọn ọmọ Israẹli lọ.” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ọlọrun àwọn Heberu ni ó farahàn wá; jọ̀wọ́, fún wa ní ààyè láti lọ sí aṣálẹ̀ ní ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ mẹta, kí á lè lọ rúbọ sí OLUWA Ọlọrun wa, kí ó má baà fi àjàkálẹ̀ àrùn tabi ogun bá wa jà.” Ṣugbọn ọba Ijipti dá wọn lóhùn pé, “Ìwọ Mose ati ìwọ Aaroni, kí ló dé tí ẹ fi kó àwọn eniyan wọnyi kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wọn? Ẹ kó wọn pada kíákíá.” Farao fi kún un pé, “Ṣé ẹ̀yin náà rí i pé àwọn eniyan yìí pọ̀ pupọ ju àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ ilẹ̀ yìí lọ, ẹ sì tún kó wọn kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wọn?” Ní ọjọ́ náà gan-an ni Farao pàṣẹ fún gbogbo àwọn ọ̀gá tí wọn ń kó àwọn ọmọ Israẹli ṣiṣẹ́ pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ fún àwọn eniyan wọnyi ní koríko láti fi ṣe bíríkì bí ẹ ti ṣe ń fún wọn tẹ́lẹ̀ mọ; ẹ jẹ́ kí wọn máa lọ kó koríko fúnra wọn. Iye bíríkì tí wọn ń ṣe tẹ́lẹ̀ kò sì gbọdọ̀ dín; nítorí pé nígbà tí iṣẹ́ kò ká wọn lára ni wọ́n ṣe ń rí ààyè pariwo pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ rúbọ sí Ọlọrun wa.’ Ẹ fi iṣẹ́ kún iṣẹ́ wọn. Nígbà tí iṣẹ́ bá wọ̀ wọ́n lọ́rùn gan-an, bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ ń parọ́ fún wọn, wọn kò ní fetí sí i.” Àwọn tí wọn ń kó àwọn ọmọ Israẹli ṣiṣẹ́ bá jáde tọ̀ wọ́n lọ, wọ́n sọ fún wọn pé, “Ẹ gbọ́ bí Farao ti wí; ó ní òun kò ní fún yín ní koríko mọ́. Ó ní kí ẹ lọ máa wá koríko fúnra yín níbikíbi tí ẹ bá ti rí. Ṣugbọn iye bíríkì tí ẹ̀ ń mọ tẹ́lẹ̀ kò gbọdọ̀ dín!” Wọ́n bá fọ́n káàkiri gbogbo ilẹ̀ Ijipti láti wá àgékù koríko. Àwọn tí wọn ń kó wọn ṣiṣẹ́ a máa fi ipá mú wọn pé, lojumọ, wọ́n gbọdọ̀ mọ iye bíríkì tí wọ́n máa ń mọ tẹ́lẹ̀, nígbà tí wọn kò tíì máa wá koríko fúnra wọn. Àwọn akóniṣiṣẹ́ Farao bẹ̀rẹ̀ sí na àwọn tí wọ́n fi ṣe olórí láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Wọn á máa bi wọ́n pé “Kí ló dé tí bíríkì tí ẹ mọ lónìí kò fi tó iye tí ó yẹ kí ẹ mọ?” Àwọn tí wọ́n fi ṣe olórí láàrin àwọn ọmọ Israẹli bá ké tọ Farao lọ, wọ́n ní, “Kí ló dé tí o fi ń ṣe báyìí sí àwa iranṣẹ rẹ? Ẹnikẹ́ni kò fún wa ní koríko, sibẹ wọ́n ní dandan, a gbọdọ̀ mọ iye bíríkì tí à ń mọ tẹ́lẹ̀. Wọ́n ń lù wá, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ará Ijipti gan-an ni wọ́n jẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà.” Ṣugbọn Farao dá wọn lóhùn pé, “Ọ̀lẹ ni yín, ẹ kò fẹ́ ṣiṣẹ́ ni ẹ fi ń sọ pé kí n jẹ́ kí ẹ lọ rúbọ sí OLUWA. Ẹ kúrò níwájú mi nisinsinyii, kí ẹ lọ máa ṣiṣẹ́ yín; kò sí ẹni tí yóo fún yín ní koríko, iye bíríkì tí ẹ̀ ń mọ tẹ́lẹ̀ kò sì gbọdọ̀ dín.” Àwọn tí wọ́n jẹ́ olórí láàrin àwọn ọmọ Israẹli rí i pé àwọn wà ninu ewu, nígbà tí wọ́n gbọ́ pé iye bíríkì tí àwọn ń mọ lojumọ kò gbọdọ̀ dín rárá. Bí wọ́n ti ń ti ọ̀dọ̀ Farao bọ̀, wọ́n lọ sọ́dọ̀ Mose ati Aaroni tí wọ́n dúró dè wọ́n, wọ́n sì sọ fún wọn pé, “Ọlọrun ni yóo dájọ́ fún yín, ẹ̀yin tí ẹ sọ wá di ẹni ìríra níwájú Farao ati àwọn iranṣẹ rẹ̀, ẹ sì ti yọ idà lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n fi pa wá.” Mose bá tún yipada sí OLUWA, ó ní, “OLUWA, kí ló dé tí o fi ṣe ibi sí àwọn eniyan wọnyi? Kí ló dé tí o fi rán mi sí wọn? Nítorí pé, láti ìgbà tí mo ti lọ sí ọ̀dọ̀ Farao láti bá a sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ, ni ó ti ń ṣe àwọn eniyan wọnyi níbi, bẹ́ẹ̀ ni o kò sì gba àwọn eniyan rẹ sílẹ̀ rárá!” Ṣugbọn OLUWA sọ fún Mose pé, “O óo rí ohun tí n óo ṣe sí ọba Farao; ó fẹ́, ó kọ̀, yóo jẹ́ kí àwọn eniyan mi lọ, fúnra rẹ̀ ni yóo sì fi ipá tì wọ́n jáde.” Ọlọrun tún sọ fún Mose pé, “Èmi ni OLUWA. Mo fara han Abrahamu, Isaaki, ati Jakọbu gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun Olodumare, ṣugbọn n kò farahàn wọ́n gẹ́gẹ́ bí OLUWA tíí ṣe orúkọ mi gan-an. Mo tún bá wọn dá majẹmu pé n óo fi ilẹ̀ Kenaani fún wọn, ilẹ̀ tí wọ́n ti jẹ́ àlejò. Mo gbọ́ ìkérora àwọn ọmọ Israẹli tí àwọn ará Ijipti dì ní ìgbèkùn, mo sì ranti majẹmu mi. Nítorí náà, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Èmi ni OLUWA, n óo yọ yín jáde kúrò lábẹ́ ẹrù wúwo tí àwọn ará Ijipti dì rù yín, n óo yọ yín kúrò ninu ìgbèkùn wọn, ipá ni n óo sì fi rà yín pada pẹlu ìdájọ́ ńlá. N óo mu yín gẹ́gẹ́ bí eniyan mi, n óo jẹ́ Ọlọrun yín; ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó fà yín yọ kúrò lábẹ́ ẹrù wúwo tí àwọn ará Ijipti dì rù yín. N óo sì ko yín wá sí ilẹ̀ tí mo búra láti fún Abrahamu, ati Isaaki ati Jakọbu; n óo fún yín gẹ́gẹ́ bí ìní, Èmi ni OLUWA.’ ” Mose sọ ọ̀rọ̀ wọnyi fún àwọn eniyan Israẹli, ṣugbọn wọn kò fetí sí ohun tí ó ń sọ, nítorí pé ìyà burúkú tí wọn ń jẹ ní oko ẹrú ti jẹ́ kí ọkàn wọn rẹ̀wẹ̀sì. OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Wọlé lọ sí ọ̀dọ̀ Farao, ọba ilẹ̀ Ijipti, kí o wí fún un pé kí ó jẹ́ kí àwọn eniyan Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.” Ṣugbọn Mose dá OLUWA lóhùn pé, “Àwọn eniyan Israẹli gan-an kò gbọ́ tèmi, báwo ni Farao yóo ṣe gbọ́, èmi akólòlò lásánlàsàn.” Ṣugbọn Ọlọrun bá Mose ati Aaroni sọ̀rọ̀, ó wá pàṣẹ ohun tí wọn yóo sọ fún àwọn eniyan Israẹli ati fún Farao, ọba Ijipti, pé kí ó kó àwọn eniyan Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. Èyí ni àkọsílẹ̀ àwọn olórí olórí ninu ìdílé wọn: Reubẹni, àkọ́bí Jakọbu bí ọmọkunrin mẹrin: Hanoku, Palu, Hesironi ati Karimi; àwọn ni olórí àwọn ìdílé ẹ̀yà Reubẹni. Simeoni bí ọmọkunrin mẹfa: Jemueli, Jamini, Ohadi, Jakini, Sohari ati Ṣaulu, tí obinrin ará Kenaani kan bí fún un; àwọn ni olórí àwọn ìdílé ẹ̀yà Simeoni. Lefi bí ọmọ mẹta: Geriṣoni, Kohati ati Merari; àwọn ni olórí àwọn ìdílé ẹ̀yà Lefi. Ọdún mẹtadinlogoje (137) ni Lefi gbé láyé. Geriṣoni bí ọmọ meji: Libini ati Ṣimei, wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé wọn. Kohati bí ọmọ mẹrin: Amramu, Iṣari, Heburoni ati Usieli. Ọdún mẹtalelaadoje (133) ni Kohati gbé láyé. Merari bí ọmọkunrin meji: Mahili ati Muṣi. Àwọn ìdílé ẹ̀yà Lefi nìwọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí arọmọdọmọ wọn. Amramu fẹ́ Jokebedi, arabinrin baba rẹ̀. Jokebedi sì bí Aaroni ati Mose fún un. Ọdún mẹtadinlogoje (137) ni Amramu gbé láyé. Iṣari bí ọmọkunrin mẹta: Kora, Nefegi ati Sikiri. Usieli bí ọmọkunrin mẹta: Miṣaeli, Elisafani ati Sitiri. Aaroni fẹ́ Eliṣeba ọmọbinrin Aminadabu tíí ṣe arabinrin Naṣoni. Àwọn ọmọ tí ó bí fún un nìwọ̀nyí: Nadabu, Abihu, Eleasari, ati Itamari. Kora bí ọmọkunrin mẹta: Asiri, Elikana ati Abiasafu; àwọn ni ìdílé Kora. Eleasari ọmọ Aaroni fẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ọmọbinrin Putieli; ó sì bí Finehasi fún un; àwọn ni olórí àwọn ìdílé ẹ̀yà Lefi. Aaroni ati Mose ni OLUWA pè, tí ó sì wí fún pé kí wọ́n kó àwọn eniyan Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. Àwọn ni wọ́n sọ fún ọba Ijipti pé kí ó dá àwọn eniyan Israẹli sílẹ̀. Ní ọjọ́ tí OLUWA bá Mose sọ̀rọ̀ ní ilẹ̀ Ijipti, OLUWA sọ fún un pé, “Èmi ni OLUWA, sọ gbogbo ohun tí mo rán ọ fún Farao, ọba Ijipti.” Ṣugbọn Mose dáhùn pé, “OLUWA, akólòlò ni mí; báwo ni ọba Farao yóo ṣe fetí sí ọ̀rọ̀ mi?” OLUWA bá dá Mose lóhùn pé, “Wò ó, mo ti sọ ọ́ di ọlọrun fún Farao, Aaroni, arakunrin rẹ ni yóo sì jẹ́ wolii rẹ. Gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ ni kí o sọ; Aaroni, arakunrin rẹ yóo sì sọ fún Farao pé kí ó jẹ́ kí àwọn eniyan Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀. Ṣugbọn n óo mú kí ọkàn Farao le, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo fi jẹ́ pé, bí ó ti wù kí iṣẹ́ ìyanu tí n óo ṣe ní ilẹ̀ Ijipti pọ̀ tó, kò ní gbọ́ tìrẹ. Nígbà náà ni n óo nawọ́ ìyà sí Ijipti, n óo sì kó àwọn ọmọ Israẹli, ìjọ eniyan mi, jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti pẹlu iṣẹ́ ìyanu ati ìdájọ́ ńlá. Àwọn ará Ijipti yóo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA, nígbà tí mo bá nawọ́ ìyà sí Ijipti tí mo sì kó àwọn eniyan Israẹli jáde kúrò láàrin wọn.” Mose ati Aaroni bá ṣe bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún wọn. Nígbà tí Mose ati Aaroni lọ bá Farao sọ̀rọ̀, Mose jẹ́ ẹni ọgọrin ọdún; Aaroni sì jẹ́ ẹni ọdún mẹtalelọgọrin. OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé, “Bí Farao bá wí pé kí ẹ ṣe iṣẹ́ ìyanu kan fún òun kí òun lè mọ̀ pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yín, kí ìwọ Mose sọ fún Aaroni pé kí ó ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Farao ọba, kí ọ̀pá náà lè di ejò.” Mose ati Aaroni bá lọ sọ́dọ̀ Farao, wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún wọn. Aaroni ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Farao ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀, ọ̀pá náà di ejò. Farao bá pe gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n, ati àwọn oṣó, ati àwọn pidánpidán tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Ijipti, àwọn náà pa idán, wọ́n ṣe bí Aaroni ti ṣe. Olukuluku wọn sọ ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀, ọ̀pá wọn sì di ejò ṣugbọn ọ̀pá Aaroni gbé gbogbo ọ̀pá tiwọn mì. Sibẹsibẹ ọkàn Farao tún le, kò sì gbọ́ tiwọn, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀. OLUWA wí fún Mose pé, “Ọkàn Farao ti le, kò sì jẹ́ kí àwọn eniyan náà lọ. Tọ Farao lọ ní òwúrọ̀, bí ó bá ti ń jáde lọ sí etídò, kí o dúró dè é ní etí bèbè odò, kí o sì mú ọ̀pá tí ó di ejò lọ́wọ́. Sọ fún un pé, ‘OLUWA, Ọlọrun àwọn Heberu rán mi sí ọ, pé kí o jẹ́ kí àwọn eniyan òun lọ, kí wọ́n lè sin òun ní aṣálẹ̀, sibẹ o kò gbọ́. OLUWA wí pé ohun tí o óo fi mọ̀ pé òun ni OLUWA nìyí: n óo fi ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ mi yìí lu odò Naili, omi odò náà yóo sì di ẹ̀jẹ̀. Gbogbo ẹja inú odò náà yóo kú, odò náà yóo sì máa rùn, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ará Ijipti kò ní lè mu omi inú rẹ̀ mọ́.’ ” OLUWA rán Mose pé, “Sọ fún Aaroni pé kí ó mú ọ̀pá rẹ̀, kí ó sì nà án sí orí gbogbo omi ilẹ̀ Ijipti, ati sórí odò wọn, ati sórí adágún tí wọ́n gbẹ́, ati gbogbo ibi tí omi dárogún sí, kí wọ́n lè di ẹ̀jẹ̀, ẹ̀jẹ̀ yóo sì wà níbi gbogbo jákèjádò ilẹ̀ Ijipti; ati omi tí ó wà ninu agbada tí wọ́n fi igi gbẹ́, ati tinú agbada tí wọ́n fi òkúta gbẹ́.” Mose ati Aaroni ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA lójú Farao ati lójú gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀. Aaroni gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè ó sì fi lu omi tí ó wà ninu odò Naili, gbogbo omi tí ó wà ninu odò náà sì di ẹ̀jẹ̀. Gbogbo ẹja tí ó wà ninu odò náà kú, odò sì bẹ̀rẹ̀ sí rùn tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ará Ijipti kò fi lè mu omi rẹ̀. Ẹ̀jẹ̀ sì wà níbi gbogbo jákèjádò ilẹ̀ Ijipti. Ṣugbọn àwọn pidánpidán ilẹ̀ Ijipti lo ọgbọ́n idán wọn, àwọn náà ṣe bí Mose ati Aaroni ti ṣe, tí ó fi jẹ́ pé ọkàn Farao túbọ̀ yigbì sí i, kò sì gbọ́ ohun tí Mose ati Aaroni wí, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, Farao yipada, ó lọ sí ilé, kò ka ọ̀rọ̀ náà sí rara. Gbogbo àwọn ará Ijipti bẹ̀rẹ̀ sí gbẹ́lẹ̀ káàkiri yíká odò Naili, pé bóyá wọn á jẹ́ rí omi mímu nítorí pé wọn kò lè mu omi odò Naili mọ́. Ọjọ́ meje kọjá, lẹ́yìn tí OLUWA ti fi ọ̀pá lu odò Naili. Lẹ́yìn náà OLUWA sọ fún Mose pé, “Lọ sí ọ̀dọ̀ Farao, kí o sì wí fún un pé, ‘OLUWA ní, “Jẹ́ kí àwọn eniyan mi lọ sìn mí. Ṣugbọn bí o bá kọ̀, tí o kò jẹ́ kí wọ́n lọ, n óo da ọ̀pọ̀lọ́ bo ilẹ̀ rẹ. Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ yóo máa gbá yìnìn ninu odò Naili, wọn yóo sì wọ inú ààfin rẹ ati yàrá tí ò ń sùn, wọn yóo gun orí ibùsùn rẹ, wọn yóo sì wọ ilé àwọn ẹmẹ̀wà rẹ, ati ti àwọn eniyan rẹ. N óo dà wọ́n sinu ilé ìdáná ati sinu àwo tí wọ́n fi ń tọ́jú oúnjẹ. Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ náà yóo máa fò mọ́ ìwọ, ati àwọn eniyan rẹ ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ.” ’ ” OLUWA rán Mose pé, “Sọ fún Aaroni pé kí ó na ọwọ́ rẹ̀ ati ọ̀pá rẹ̀ sórí àwọn odò ati àwọn adágún tí wọ́n gbẹ́, ati sórí gbogbo ibi tí omi dárogún sí, kí àwọn ọ̀pọ̀lọ́ lè jáde sórí ilẹ̀ Ijipti.” Aaroni bá na ọwọ́ rẹ̀ sí orí gbogbo omi ilẹ̀ Ijipti, ọ̀pọ̀lọ́ bá wọ́ jáde, wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀ Ijipti. Àwọn pidánpidán náà ṣe bẹ́ẹ̀ pẹlu ọgbọ́n idán wọn, wọ́n mú kí ọ̀pọ̀lọ́ bo ilẹ̀ Ijipti. Nígbà náà ni Farao pe Mose ati Aaroni, ó ní, “Ẹ bẹ OLUWA kí ó kó ọ̀pọ̀lọ́ kúrò lọ́dọ̀ èmi ati àwọn eniyan mi, n óo sì jẹ́ kí àwọn ará Israẹli lọ rúbọ sí OLUWA.” Mose dá Farao lóhùn pé, “Sọ ìgbà tí o fẹ́ kí n gbadura fún ìwọ ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ, ati àwọn eniyan rẹ, kí Ọlọrun lè run gbogbo àwọn ọ̀pọ̀lọ́ tí wọ́n wà lọ́dọ̀ yín, ati ninu ilé yín; kí ó sì jẹ́ pé kìkì odò Naili nìkan ni ọ̀pọ̀lọ́ yóo kù sí.” Ọba dáhùn pé, “Ní ọ̀la.” Mose bá wí pé, “Bí o ti wí gan-an ni yóo rí, kí o lè mọ̀ pé kò sí ẹlòmíràn tí ó dàbí OLUWA Ọlọrun wa. Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ náà yóo kúrò lọ́dọ̀ rẹ, ati ninu àwọn ilé rẹ, ati lọ́dọ̀ àwọn ẹmẹ̀wà rẹ, ati lọ́dọ̀ àwọn eniyan rẹ; kìkì odò Naili nìkan ni ọ̀pọ̀lọ́ yóo kù sí.” Mose ati Aaroni bá jáde kúrò níwájú Farao, Mose gbadura sí OLUWA pé kí ó mú àwọn ọ̀pọ̀lọ́ náà kúrò, gẹ́gẹ́ bí òun ati Farao ti jọ ṣe àdéhùn. OLUWA ṣe ohun tí Mose fi adura bèèrè, àwọn ọ̀pọ̀lọ́ tí wọ́n wà ninu gbogbo ilé, ati ní àgbàlá, ati ní gbogbo oko sì kú. Wọ́n kó wọn jọ ní òkítì òkítì, gbogbo ìlú sì bẹ̀rẹ̀ sí rùn. Nígbà tí Farao rí i pé gbogbo ọ̀pọ̀lọ́ náà kú tán, ọkàn rẹ̀ tún le, kò sì ṣe ohun tí Mose ati Aaroni wí mọ́, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀. OLUWA rán Mose pé, kí ó sọ fún Aaroni pé kí ó na ọ̀pá rẹ̀ jáde, kí ó sì fi lu erùpẹ̀ ilẹ̀, kí gbogbo rẹ̀ sì di iná orí ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti. Wọ́n ṣe bí OLUWA ti wí; Aaroni na ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀, ó fi lu erùpẹ̀ ilẹ̀, iná sì bo àwọn eniyan ati àwọn ẹranko; gbogbo erùpẹ̀ ilẹ̀ sì di iná ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti. Àwọn pidánpidán náà gbìyànjú láti mú kí iná jáde pẹlu ọgbọ́n idán wọn, ṣugbọn wọn kò lè ṣe é. Iná bo gbogbo eniyan ati àwọn ẹranko. Àwọn pidánpidán náà sọ fún Farao pé, “Iṣẹ́ Ọlọrun ni èyí.” Ṣugbọn ọkàn Farao le, kò sì fetí sí ọ̀rọ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀. OLUWA bá tún sọ fún Mose pé, “Dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, kí o lọ dúró de ọba Farao bí ó bá ti ń jáde lọ sétí odò, wí fún un pé, kí ó gbọ́ ohun tí èmi OLUWA wí, pé kí ó jẹ́ kí àwọn eniyan mi lọ sìn mí. Wí fún un pé, mo ní, tí kò bá jẹ́ kí wọ́n lọ n óo da eṣinṣin bo òun ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ati àwọn eniyan rẹ̀, àwọn ará ilé rẹ̀ ati ti àwọn ará Ijipti, orí ilẹ̀ tí wọ́n dúró lé yóo sì kún fún ọ̀wọ́ eṣinṣin. Ṣugbọn ní ọjọ́ náà, èmi OLUWA yóo ya ilẹ̀ Goṣeni sọ́tọ̀, níbi tí àwọn eniyan mi ń gbé, kí ọ̀wọ́ eṣinṣin má baà lè débẹ̀, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi ni OLUWA ní ayé yìí. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe fi ààlà sí ààrin àwọn eniyan mi ati àwọn eniyan rẹ̀. Ní ọ̀la ni iṣẹ́ ìyanu náà yóo ṣẹ.” OLUWA ṣe bẹ́ẹ̀; ọ̀wọ́ eṣinṣin wọ inú ilé Farao ati ti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ati gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Ijipti. Eṣinṣin sì ba ilẹ̀ náà jẹ́. Farao bá pe Mose ati Aaroni, ó ní, “Ẹ lọ rúbọ sí Ọlọrun yín, ṣugbọn ní ilẹ̀ yìí ni kí ẹ ti rú u.” Mose dá a lóhùn pé, “Kò ní tọ̀nà bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀; nítorí pé àwọn nǹkan mìíràn lè wà ninu ohun tí a óo fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun wa tí ó lè jẹ́ ìríra fún àwọn ará Ijipti. Bí a bá fi ohunkohun rúbọ tí ó jẹ́ ìríra lójú àwọn ará Ijipti, ṣé wọn kò ní sọ wá ní òkúta pa? A níláti lọ sinu aṣálẹ̀ ní ìrìn ọjọ́ mẹta kí á sì rúbọ sí OLUWA Ọlọrun wa gẹ́gẹ́ bí ó ti pa á láṣẹ fún wa.” Farao dáhùn, ó ní, “N óo fún yín láàyè láti lọ rúbọ sí OLUWA Ọlọrun yín ninu aṣalẹ̀, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ lọ jìnnà; ati pé, mo fẹ́ kí ẹ bá mi bẹ Ọlọrun yín.” Mose bá dáhùn pé, “Wò ó, ń óo jáde kúrò ní iwájú rẹ nisinsinyii, n óo sì lọ gbadura sí OLUWA, kí ọ̀wọ́ eṣinṣin wọnyi lè lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ ní ọ̀la, kí wọ́n sì kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹmẹ̀wà rẹ ati àwọn eniyan rẹ pẹlu ṣugbọn kí Farao má tún dalẹ̀, kí ó má wí pé àwọn eniyan Israẹli kò gbọdọ̀ lọ rúbọ sí OLUWA.” Mose bá jáde kúrò níwájú Farao, ó lọ gbadura sí OLUWA, OLUWA sì ṣe ohun tí Mose bèèrè, ó mú kí ọ̀wọ́ eṣinṣin náà kúrò lọ́dọ̀ Farao ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ati àwọn eniyan rẹ̀. Ó mú kí gbogbo eṣinṣin náà kúrò láìku ẹyọ kan. Ṣugbọn ọkàn Farao tún le, kò sì jẹ́ kí àwọn eniyan náà lọ. Ọlọrun tún sọ fún Mose pé kí ó wọlé tọ Farao lọ, kí ó sì sọ fún un pé kí ó gbọ́ ohun tí òun OLUWA Ọlọrun àwọn Heberu wí, kí ó jẹ́ kí àwọn eniyan òun lọ sìn òun. Ati pé, bí ó bá kọ̀, tí kò jẹ́ kí wọ́n lọ, àjàkálẹ̀ àrùn yóo ti ọwọ́ òun OLUWA wá sórí gbogbo ẹran ọ̀sìn rẹ̀ tí wọ́n wà ní pápá, ati àwọn ẹṣin rẹ̀, ati àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ati àwọn ràkúnmí rẹ̀, ati àwọn agbo mààlúù rẹ̀, ati àwọn agbo aguntan rẹ̀. Ó ní, Ṣugbọn òun yóo ya àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ará Ijipti, ẹyọ kan ṣoṣo kò ní kú ninu gbogbo àwọn ẹran tíí ṣe ti àwọn ọmọ Israẹli. OLUWA bá dá àkókò kan, ó ní, “Ní ọ̀la ni èmi OLUWA, yóo ṣe ohun tí mo wí yìí ní ilẹ̀ Ijipti.” Nígbà tí ó di ọjọ́ keji OLUWA ṣe bí ó ti wí; gbogbo àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ará Ijipti kú, ṣugbọn ẹyọ kan ṣoṣo kò kú ninu ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli. Farao bá ranṣẹ lọ wo àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli, ó sì rí i pé ẹyọ kan kò kú ninu wọn. Sibẹsibẹ ọkàn Farao le, kò sì jẹ́ kí àwọn eniyan náà lọ. OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé kí wọn bu ẹ̀kúnwọ́ eérú bíi mélòó kan ninu ẹbu, kí Mose dà á sí ojú ọ̀run lójú Farao, yóo sì di eruku lẹ́búlẹ́bú lórí gbogbo ilẹ̀ Ijipti, yóo di oówo tí yóo máa di egbò lára eniyan ati ẹranko, ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti. Mose ati Aaroni bá bu eérú ninu ẹbu, wọ́n dúró níwájú Farao. Mose da eérú náà sókè sí ojú ọ̀run, eérú náà bá di oówo tí ń di egbò lára eniyan ati ẹranko. Àwọn pidánpidán kò lè dúró níwájú Mose, nítorí pe oówo bo àwọn náà ati gbogbo àwọn eniyan ilẹ̀ Ijipti. Ṣugbọn OLUWA mú kí ọkàn Farao le, kò sì gbọ́ tiwọn, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ fún Mose. OLUWA tún sọ fún Mose pé kí ó dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, kí ó lọ siwaju Farao, kí ó sì sọ fún un pé kí ó gbọ́ ohun tí òun OLUWA Ọlọrun àwọn Heberu wí, kí ó jẹ́ kí àwọn eniyan òun lọ sin òun. Nítorí pé lọ́tẹ̀ yìí, òun óo da gbogbo àjàkálẹ̀ àrùn òun bo Farao gan-an, ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀, ati àwọn eniyan rẹ̀, kí ó lè mọ̀ pé kò sí ẹni tí ó dàbí òun OLUWA ní gbogbo ayé. Kí ó ranti pé, bí òun OLUWA ti nawọ́ ìyà sí òun ati àwọn eniyan rẹ̀, tí òun sì ti da àjàkálẹ̀ àrùn bò wọ́n; òun ìbá ti pa wọ́n run kúrò lórí ilẹ̀ ayé, ṣugbọn ìdí pataki tí òun fi jẹ́ kí wọ́n wà láàyè ni láti fi agbára òun hàn Farao, kí wọ́n lè máa ròyìn orúkọ òun OLUWA káàkiri gbogbo ayé. Ó ní Farao sì tún ń gbé ara rẹ̀ ga sí àwọn eniyan òun, kò jẹ́ kí wọ́n lọ. OLUWA ní, “Wò ó, níwòyí ọ̀la, n óo da yìnyín bo ilẹ̀, irú èyí tí kò sí ní ilẹ̀ Ijipti rí, láti ọjọ́ tí wọ́n ti tẹ̀ ẹ́ dó títí di òní yìí. Nítorí náà, yára ranṣẹ lọ kó gbogbo àwọn ẹran rẹ tí wọ́n wà ninu pápá síbi ìpamọ́, nítorí pé yìnyín yóo rọ̀ sórí eniyan ati ẹranko tí ó bá wà ní pápá, tí wọn kò bá kó wọlé, gbogbo wọn ni yóo sì kú.” Nítorí náà gbogbo àwọn tí wọ́n bẹ̀rù ọ̀rọ̀ OLUWA ninu àwọn iranṣẹ Farao pe àwọn ẹrú wọn wálé, wọ́n sì kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn wálé pẹlu. Ṣugbọn àwọn tí wọn kò ka ọ̀rọ̀ OLUWA sí fi àwọn ẹrú ati àwọn ohun ọ̀sìn wọn sílẹ̀ ninu pápá. OLUWA sọ fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ sójú ọ̀run, kí yìnyín lè bọ́ kí ó sì bo ilẹ̀ Ijipti, ati eniyan, ati ẹranko, ati gbogbo ewéko inú ìgbẹ́.” Mose bá na ọ̀pá rẹ̀ sójú ọ̀run, Ọlọrun sì da ààrá ati yìnyín ati iná bo ilẹ̀, Ọlọrun sì rọ̀jò yìnyín sórí ilẹ̀ Ijipti. Yìnyín ń bọ́, mànàmáná sì ń kọ yànràn ninu yìnyín náà. Yìnyín náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́; kò tíì sí irú rẹ̀ rí ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti láti ìgbà tí ó ti di orílẹ̀-èdè. Gbogbo ohun tí ó wà ninu oko ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti ni yìnyín náà dà lulẹ̀, ati eniyan ati ẹranko; o sì wó gbogbo àwọn ohun ọ̀gbìn oko ati gbogbo igi lulẹ̀. Àfi ilẹ̀ Goṣeni, níbi tí àwọn ọmọ Israẹli ń gbé nìkan ni yìnyín yìí kò dé. Farao bá ranṣẹ pe Mose ati Aaroni, ó sọ fún wọn pé, “Mo ti dẹ́ṣẹ̀ nisinsinyii; OLUWA jàre, èmi ati àwọn eniyan mi ni a jẹ̀bi. Ẹ bẹ OLUWA fún mi nítorí pé yìnyín ati ààrá yìí tó gẹ́ẹ́, n óo jẹ́ kí ẹ lọ, n kò ní da yín dúró mọ́.” Mose bá dá Farao lóhùn pé, “Bí mo bá ti jáde kúrò ninu ìlú n óo gbadura sí OLUWA, ààrá kò ní sán mọ́, bẹ́ẹ̀ ni yìnyín kò ní bọ́ mọ́, kí o lè mọ̀ pé, ti OLUWA ni ilẹ̀. Ṣugbọn mo mọ̀ pé ìwọ ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ kò bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun.” Gbogbo ọ̀gbọ̀ ati ọkà Baali tí ó wà lóko ni ó ti bàjẹ́ patapata, nítorí pé ọkà baali ati ọ̀gbọ̀ náà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí so ni. Ṣugbọn ọkà alikama ati ọkà ria kò bàjẹ́, nítorí pé wọn kò tètè hù. Mose bá kúrò lọ́dọ̀ Farao, ó jáde kúrò ní ìlú; ó gbadura sí OLUWA, ààrá tí ń sán ati yìnyín tí ń bọ́ sì dáwọ́ dúró, òjò náà sì dá lórí ilẹ̀. Ṣugbọn nígbà tí Farao rí i pé òjò ti dá, ati pé yìnyín ati ààrá ti dáwọ́ dúró, ó tún dẹ́ṣẹ̀, ọkàn rẹ̀ tún le, ati ti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀. Ọkàn rẹ̀ tún le, kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli lọ, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ láti ẹnu Mose. OLUWA bá pe Mose, ó ní, “Wọlé tọ Farao lọ, nítorí pé mo tún ti mú ọkàn rẹ̀ le, ati ti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀, kí n lè ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu mi láàrin wọn. Kí ẹ̀yin náà sì lè sọ fún àwọn ọmọ ati àwọn ọmọ ọmọ yín, irú ohun tí mo fi ojú wọn rí, ati irú iṣẹ́ ìyanu tí mo ṣe láàrin wọn; kí ẹ lè mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” Nítorí náà, Mose ati Aaroni lọ, wọ́n sì wí fún Farao pé, “OLUWA Ọlọrun àwọn Heberu ní kí á bèèrè lọ́wọ́ rẹ pé, yóo ti pẹ́ tó tí o óo fi kọ̀ láti rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú òun Ọlọrun? Ó ní, kí o jẹ́ kí àwọn eniyan òun lọ kí wọ́n lè sin òun. Nítorí pé bí o bá kọ̀, tí o kò jẹ́ kí àwọn eniyan òun lọ, ó ní òun yóo mú kí eṣú wọ ilẹ̀ rẹ lọ́la. Àwọn eṣú náà yóo sì bo gbogbo ilẹ̀, tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ní rí ilẹ̀ rárá, wọn yóo sì jẹ gbogbo ohun tí ó ṣẹ́kù tí yìnyín kò pa, wọn yóo jẹ gbogbo igi rẹ tí ó wà ninu pápá oko. Wọn yóo rọ́ kún gbogbo ààfin rẹ ati ilé gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà rẹ ati ilé gbogbo àwọn ará Ijipti, àwọn eṣú náà yóo burú ju ohunkohun tí àwọn baba ati àwọn baba ńlá yín ti rí rí lọ, láti ọjọ́ tí wọ́n ti dáyé títí di òní olónìí.” Mose bá yipada kúrò níwájú Farao. Àwọn ẹmẹ̀wà Farao sọ fún un pé, “Kabiyesi, ìgbà wo ni ọkunrin yìí yóo yọ wá lẹ́nu dà? Ẹ jẹ́ kí wọ́n lọ kí wọ́n lè lọ sin OLUWA Ọlọrun wọn. Àbí kò tíì hàn sí kabiyesi báyìí pé gbogbo Ijipti tí ń parun tán lọ ni?” Wọ́n bá mú Mose ati Aaroni pada tọ Farao lọ. Farao ní kí wọ́n lọ sin OLUWA Ọlọrun wọn, ṣugbọn ó bèèrè pé àwọn wo gan-an ni yóo lọ? Mose dáhùn pé, “Gbogbo wa ni à ń lọ, ati àgbà ati èwe; ati ọkunrin ati obinrin, ati gbogbo agbo mààlúù wa, ati gbogbo agbo ẹran wa, nítorí pé a níláti lọ ṣe àjọ̀dún kan fún OLUWA.” Farao bá dáhùn, ó ní, “Kí OLUWA wà pẹlu yín bí mo bá jẹ́ kí ẹ̀yin ati àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ yín lọ. Wò ó, ète burúkú wà ní ọkàn yín. N ò gbà! Ẹ̀yin ọkunrin nìkan ni kí ẹ lọ sin OLUWA; nítorí pé bẹ́ẹ̀ gan-an ni ẹ fẹ́ àbí?” Wọ́n bá lé wọn jáde kúrò níwájú Farao. OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ sórí ilẹ̀ Ijipti, kí eṣú lè tú jáde, kí wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀ náà, kí wọ́n jẹ gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó ṣẹ́kù ní ilẹ̀ náà tí yìnyín kò pa.” Mose bá gbé ọ̀pá rẹ̀, ó nà án sókè, sórí gbogbo ilẹ̀ Ijipti. OLUWA bá mú kí afẹ́fẹ́ kan fẹ́ wá láti ìlà oòrùn, afẹ́fẹ́ náà fẹ́ sórí gbogbo ilẹ̀ náà, ní gbogbo ọ̀sán ati ní gbogbo òru ọjọ́ náà. Nígbà tí yóo fi di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, afẹ́fẹ́ ti kó eṣú dé. Eṣú bo gbogbo ilẹ̀ Ijipti, wọ́n sì bà sí gbogbo ilẹ̀. Wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé irú rẹ̀ kò sí rí, irú rẹ̀ kò sì tún tíì ṣẹlẹ̀ mọ́ láti ìgbà náà. Nítorí pé wọ́n bo gbogbo ilẹ̀ patapata, tóbẹ́ẹ̀ tí gbogbo ojú ọ̀run ṣókùnkùn dudu, wọ́n sì jẹ gbogbo ewé, ati gbogbo èso tí ń bẹ lórí igi, ati koríko tí ó ṣẹ́kù tí yìnyín kò pa. Ẹyọ ewé kan kò kù lórí igi, tabi koríko, tabi ohun ọ̀gbìn kan ninu oko, jákèjádò ilẹ̀ Ijipti. Farao bá yára pe Mose ati Aaroni, ó ní, “Mo ti ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun yín ati sí ẹ̀yin pàápàá. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí, ẹ bá mi bẹ OLUWA Ọlọrun yín ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo péré yìí, kí ó jọ̀wọ́ mú ikú yìí kúrò lọ́dọ̀ mi.” Mose bá jáde kúrò níwájú Farao, ó lọ gbadura sí OLUWA. OLUWA bá yí afẹ́fẹ́ líle ìwọ̀ oòrùn pada, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ àwọn eṣú náà lọ sí inú Òkun Pupa, ẹyọ eṣú kan ṣoṣo kò sì kù mọ́ ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti. Ṣugbọn OLUWA tún mú kí ọkàn Farao le, kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli lọ. OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ojú ọ̀run, kí òkùnkùn lè ṣú bo gbogbo ilẹ̀ Ijipti, òkùnkùn biribiri tí eniyan fẹ́rẹ̀ lè dì mú.” Mose bá gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí ojú ọ̀run, òkùnkùn biribiri sì ṣú bo gbogbo ilẹ̀ Ijipti fún odidi ọjọ́ mẹta. Wọn kò lè rí ara wọn, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò sì dìde kúrò níbi tí ó wà fún ọjọ́ mẹta. Ṣugbọn ìmọ́lẹ̀ wà ní gbogbo ibi tí àwọn ọmọ Israẹli ń gbé. Farao bá tún ranṣẹ lọ pe Mose, ó ní, “Ẹ lọ sin Ọlọrun yín, ẹ máa kó àwọn ọmọ yín lọ pẹlu, ṣugbọn ẹ fi agbo aguntan yín ati agbo ẹran yín sílẹ̀.” Mose dáhùn pé, “O níláti jẹ́ kí á kó ẹran tí a óo fi rúbọ lọ́wọ́, ati èyí tí a óo fi rúbọ sísun sí OLUWA Ọlọrun wa. A níláti kó àwọn ẹran ọ̀sìn wa lọ, a kò ní fi ohunkohun sílẹ̀ lẹ́yìn, nítorí pé ninu wọn ni a óo ti mú láti fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun wa; a kò sì tíì mọ ohun tí a óo fi rúbọ, àfi ìgbà tí a bá débẹ̀.” Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun mú kí ọkàn Farao le, kò sì jẹ́ kí wọ́n lọ. Farao bá lé Mose, ó ní, “Kúrò lọ́dọ̀ mi; kí o sì ṣọ́ra rẹ gidigidi, n kò gbọdọ̀ tún rí ọ níwájú mi mọ́; ní ọjọ́ tí mo bá tún fi ojú kàn ọ́, ọjọ́ náà ni o óo kú!” Mose bá dáhùn, ó ní, “Bí o ti wí gan-an ni yóo rí. N kò ní dé iwájú rẹ mọ́.” Nígbà tí ó yá, OLUWA sọ fún Mose pé, “Ó ku ìyọnu kan péré, tí n óo mú bá Farao ati ilẹ̀ Ijipti, lẹ́yìn náà yóo jẹ́ kí ẹ lọ. Nígbà tí ó bá gbà kí ẹ lọ, òun fúnra rẹ̀ ni yóo tì yín jáde patapata. Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí olukuluku tọ aládùúgbò rẹ̀ lọ, ati ọkunrin ati obinrin wọn, kí wọ́n lọ tọrọ nǹkan ọ̀ṣọ́ fadaka ati ti wúrà.” OLUWA jẹ́ kí àwọn eniyan Israẹli bá ojurere àwọn ará Ijipti pàdé, ati pé àwọn ará Ijipti ati àwọn ẹmẹ̀wà Farao ati àwọn eniyan rẹ̀ ka Mose kún eniyan pataki. Mose bá sọ fún Farao pé, “OLUWA ní, nígbà tí ó bá di ọ̀gànjọ́ òru, òun yóo la ilẹ̀ Ijipti kọjá, gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Ijipti ni yóo sì kú. Bẹ̀rẹ̀ láti orí àkọ́bí Farao, tí ó jókòó lórí ìtẹ́, títí kan àkọ́bí iranṣẹbinrin tí ń lọ ọkà, ati àkọ́bí gbogbo ẹran ọ̀sìn. Ariwo ẹkún ńlá yóo sọ ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti, irú èyí tí kò ṣẹlẹ̀ rí, tí kò sì tún ní sí irú rẹ̀ mọ́. Ṣugbọn ajá kò tilẹ̀ ní gbó ẹnikẹ́ni tabi ẹran ọ̀sìn kan, jákèjádò ààrin àwọn ọmọ Israẹli; kí ẹ lè mọ̀ pé OLUWA fi ìyàtọ̀ sí ààrin àwọn ará Ijipti ati àwọn ọmọ Israẹli. Gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà rẹ wọnyi yóo sì tọ̀ mí wá, wọn yóo fi orí balẹ̀ fún mi, wọn yóo wí pé kí n máa lọ, èmi ati gbogbo àwọn eniyan mi! Lẹ́yìn náà ni n óo jáde lọ.” Mose bá fi tìbínú-tìbínú jáde kúrò níwájú Farao. Lẹ́yìn náà OLUWA sọ fún Mose pé, “Farao kò ní gba ọ̀rọ̀ rẹ, kí iṣẹ́ ìyanu mi baà lè di pupọ ní ilẹ̀ Ijipti.” Mose ati Aaroni ṣe gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí wọn ṣe níwájú Farao, ṣugbọn OLUWA sì mú kí ọkàn Farao le, kò sì jẹ́ kí àwọn eniyan Israẹli lọ kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀. OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni ní ilẹ̀ Ijipti pé, “Oṣù yìí ni yóo jẹ́ oṣù kinni ọdún fún yín. Ẹ sọ fún gbogbo ìjọ eniyan Israẹli pé, ní ọjọ́ kẹwaa oṣù yìí, ọkunrin kọ̀ọ̀kan ninu ìdílé kọ̀ọ̀kan yóo mú ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan tabi àwọ́nsìn kọ̀ọ̀kan; ọ̀dọ́ aguntan kan fún ilé kan. Bí ìdílé kan bá wà tí ó kéré jù láti jẹ ẹran ọ̀dọ́ aguntan kan tán, ìdílé yìí yóo darapọ̀ mọ́ ìdílé mìíràn ní àdúgbò rẹ̀, wọn yóo sì pín ẹran tí wọ́n bá pa gẹ́gẹ́ bí iye eniyan tí ó wà ninu ìdílé mejeeji, iye eniyan tí ó bá lè jẹ àgbò kan tán ni yóo darapọ̀ láti pín ọ̀dọ́ aguntan náà. Ọ̀dọ́ aguntan tabi àwọ́nsìn ewúrẹ́ náà kò gbọdọ̀ lábàwọ́n, ó lè jẹ́ àgbò tabi òbúkọ ọlọ́dún kan. Wọ́n óo so ẹran wọn mọ́lẹ̀ títí di ọjọ́ kẹrinla oṣù yìí. Nígbà tí ó bá di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, gbogbo ìjọ eniyan Israẹli yóo pa ẹran wọn. Wọn yóo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ẹran náà, wọn yóo fi kun àtẹ́rígbà ati ara òpó ìlẹ̀kùn mejeeji ilé tí wọn yóo ti jẹ ẹran náà. Alẹ́ ọjọ́ náà ni kí wọ́n sun ẹran náà, kí wọ́n sì jẹ ẹ́ pẹlu burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, ati ewébẹ̀ tí ó korò bí ewúro. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ninu ẹran yìí ní tútù, tabi bíbọ̀; sísun ni kí ẹ sun ún; ati orí rẹ̀ ati ẹsẹ̀ rẹ̀, ati àwọn nǹkan inú rẹ̀. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó ṣẹ́kù di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, bí ohunkohun bá ṣẹ́kù, ẹ dáná sun ún. Bí ẹ ó ṣe jẹ ẹ́ nìyí: ẹ di àmùrè yín mọ́ ẹ̀gbẹ́ yín, ẹ wọ bàtà yín, ẹ mú ọ̀pá yín lọ́wọ́; ìkánjú ni kí ẹ fi jẹ ẹ́, nítorí pé oúnjẹ ìrékọjá fún OLUWA ni. “Nítorí pé, ní òru ọjọ́ náà ni n óo la gbogbo ilẹ̀ Ijipti kọjá, n óo pa gbogbo àkọ́bí ilẹ̀ náà, ati ti eniyan ati ti ẹranko, n óo sì jẹ gbogbo àwọn oriṣa ilẹ̀ Ijipti níyà. Èmi ni OLUWA. Ẹ̀jẹ̀ tí ẹ bá fi kun àtẹ́rígbà ìlẹ̀kùn gbogbo ilé yín ni yóo jẹ́ àmì láti fi gbogbo ibi tí ẹ bá wà hàn. Nígbà tí mo bá rí ẹ̀jẹ̀ náà, n óo re yín kọjá; n kò ní fi àjàkálẹ̀ àrùn ba yín jà láti pa yín run nígbà tí mo bá ń jẹ àwọn eniyan ilẹ̀ Ijipti níyà. Ọjọ́ ìrántí ni ọjọ́ yìí yóo jẹ́ fún yín, ní ọdọọdún ni ẹ óo sì máa ṣe àjọ̀dún rẹ̀ fún OLUWA; àwọn arọmọdọmọ yín yóo sì máa ṣe àjọ̀dún yìí bí ìlànà, gẹ́gẹ́ bí ohun ìrántí títí lae. “Ọjọ́ meje ni ẹ óo fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu. Láti ọjọ́ kinni ni kí ẹ ti mú gbogbo ìwúkàrà kúrò ninu ilé yín, nítorí pé bí ẹnikẹ́ni bá jẹ burẹdi tí ó ní ìwúkàrà ninu láti ọjọ́ kinni títí di ọjọ́ keje, a kò ní ka irú ẹni bẹ́ẹ̀ kún àwọn eniyan Israẹli mọ́. Ní ọjọ́ kinni ati ní ọjọ́ keje, ẹ óo péjọ pọ̀ láti jọ́sìn. Ní ọjọ́ mejeeje yìí, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ rárá, àfi oúnjẹ tí ẹ óo bá jẹ nìkan ni ẹ lè sè. Ẹ óo máa ṣe àjọ̀dún ìrántí àjọ àìwúkàrà, nítorí ọjọ́ yìí ni ọjọ́ tí mo ko yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. Nítorí náà ẹ óo máa ṣe ìrántí ọjọ́ náà bí ìlànà ati ẹ̀yin ati àwọn arọmọdọmọ yín títí lae. Láti ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrinla oṣù kinni yìí títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kọkanlelogun oṣù náà, burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ni ẹ gbọdọ̀ máa jẹ. Kò gbọdọ̀ sí ìwúkàrà ninu ilé yín fún ọjọ́ mejeeje, nítorí pé bí ẹnikẹ́ni bá jẹ burẹdi tí ó ní ìwúkàrà ninu, a kò ní ka irú ẹni bẹ́ẹ̀ kún àwọn eniyan Israẹli mọ́, kì báà jẹ́ àlejò tabi onílé ní ilẹ̀ náà. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó ní ìwúkàrà ninu; ninu gbogbo ilé yín patapata, burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu ni ẹ gbọdọ̀ máa jẹ.” Mose bá pe gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli jọ, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ ṣa ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan ní ìdílé yín kọ̀ọ̀kan, kí ẹ sì pa á fún ìrékọjá. Ẹ mú ìdì ewé hisopu, kí ẹ tì í bọ ẹ̀jẹ̀ tí ẹ bá gbè sinu àwo kòtò kan, kí ẹ fi ẹ̀jẹ̀ náà kun àtẹ́rígbà ati òpó ìlẹ̀kùn mejeeji. Ẹnikẹ́ni ninu yín kò sì gbọdọ̀ jáde ninu ilé títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji. Nítorí pé, OLUWA yóo rékọjá, yóo sì pa àwọn ará Ijipti. Ṣugbọn nígbà tí ó bá rí ẹ̀jẹ̀ lára àtẹ́rígbà ati lára òpó ẹnu ọ̀nà mejeeji, OLUWA yóo ré ẹnu ọ̀nà náà kọjá, kò sì ní jẹ́ kí apanirun wọ ilé yín láti pa yín. Ẹ̀yin ati àwọn arọmọdọmọ yín, ẹ gbọdọ̀ máa pa ìlànà yìí mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin títí lae. Nígbà tí ẹ bá sì dé ilẹ̀ tí OLUWA yóo fún yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí, ẹ gbọdọ̀ máa ṣe ìsìn yìí. Nígbà tí àwọn ọmọ yín bá sì bi yín léèrè pé, ‘Kí ni ìtumọ̀ ìsìn yìí?’ ẹ óo dá wọn lóhùn pé, ‘Ẹbọ ìrékọjá OLUWA ni, nítorí pé ó ré ilé àwọn eniyan Israẹli kọjá ní Ijipti, nígbà tí ó ń pa àwọn ará Ijipti, ṣugbọn ó dá àwọn ilé wa sí.’ ” Àwọn eniyan Israẹli wólẹ̀, wọ́n sì sin OLUWA. Wọ́n bá lọ, wọ́n sì ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose ati Aaroni. Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́ òru, OLUWA lu gbogbo àwọn àkọ́bí ilẹ̀ Ijipti pa, ó bẹ̀rẹ̀ láti orí àrẹ̀mọ ọba Farao tí ó wà lórí ìtẹ́, títí kan àkọ́bí ẹrú tí ó wà ninu ọgbà ẹ̀wọ̀n, ati àkọ́bí gbogbo ẹran ọ̀sìn. Farao bá dìde ní ọ̀gànjọ́ òru, òun ati gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀, ati gbogbo àwọn ará Ijipti. Igbe ẹkún ńlá sì sọ ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti, nítorí pé kò sí ẹyọ ilé kan tí eniyan kò ti kú. Farao bá ranṣẹ pe Mose ati Aaroni ní òru ọjọ́ náà, ó ní, “Ẹ gbéra, ẹ máa lọ, ẹ jáde kúrò láàrin àwọn eniyan mi, ati ẹ̀yin ati àwọn eniyan Israẹli, ẹ lọ sin OLUWA yín bí ẹ ti wí. Ẹ máa kó àwọn agbo mààlúù yín lọ, ati agbo aguntan yín, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti wí. Ẹ máa lọ; ṣugbọn ẹ súre fún èmi náà!” Àwọn ará Ijipti bá ń kán àwọn eniyan náà lójú láti tètè máa lọ. Wọ́n ní bí wọn kò bá tètè lọ, gbogbo àwọn ni àwọn yóo di òkú. Àwọn eniyan náà bá mú àkàrà tí wọ́n ti pò, ṣugbọn tí wọn kò tíì fi ìwúkàrà sí, wọ́n sì fi aṣọ so ọpọ́n ìpòkàrà wọn, wọ́n gbé e kọ́ èjìká. Àwọn eniyan náà ṣe bí Mose ti sọ fún wọn, olukuluku wọn ti tọ àwọn ará Ijipti lọ, wọ́n ti tọrọ ohun ọ̀ṣọ́ fadaka ati ti wúrà ati aṣọ. OLUWA sì jẹ́ kí wọ́n bá ojurere àwọn ará Ijipti pàdé, gbogbo ohun tí wọ́n tọrọ pátá ni àwọn ará Ijipti fún wọn. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan Israẹli ṣe, tí wọ́n sì fi kó ohun ọ̀ṣọ́ àwọn ará Ijipti lọ. Àwọn eniyan Israẹli gbéra, wọ́n rìn láti Ramesesi lọ sí Sukotu. Iye àwọn eniyan náà tó ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ (600,000) ọkunrin, láìka àwọn obinrin ati àwọn ọmọde. Ọpọlọpọ àwọn mìíràn ni wọ́n bá wọn lọ, pẹlu ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn ati agbo aguntan ati agbo mààlúù. Wọ́n mú ìyẹ̀fun tí wọ́n ti pò ní ilẹ̀ Ijipti, wọ́n fi ṣe burẹdi tí kò ní ìwúkàrà, nítorí pé lílé ni àwọn ará Ijipti lé wọn jáde, wọn kò sì lè dúró mú oúnjẹ mìíràn lọ́wọ́. Àkókò tí àwọn ọmọ Israẹli gbé ní ilẹ̀ Ijipti jẹ́ irinwo ọdún ó lé ọgbọ̀n (430). Ọjọ́ tí ó pé irinwo ọdún ó lé ọgbọ̀n (430) gééré, tí wọ́n ti dé ilẹ̀ Ijipti; ni àwọn eniyan OLUWA jáde kúrò níbẹ̀. Ṣíṣọ́ ni OLUWA ń ṣọ́ wọn ní gbogbo òru ọjọ́ náà títí ó fi kó wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. Àwọn eniyan Israẹli ya alẹ́ ọjọ́ náà sọ́tọ̀ fún OLUWA, láti ìrandíran wọn. Ní ọdọọdún ni wọ́n máa ń ṣọ́nà ní òru ní ìrántí òru àyájọ́ ọjọ́ náà. OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé, “Òfin àjọ ìrékọjá nìwọ̀nyí: àlejò kankan kò gbọdọ̀ ba yín jẹ oúnjẹ àjọ ìrékọjá. Ṣugbọn àwọn ẹrú tí ẹ fi owó rà, tí ẹ sì kọ ní ilà abẹ́ lè bá yín jẹ ẹ́. Àlejò kankan tabi alágbàṣe kò gbọdọ̀ ba yín jẹ ẹ́. Ilé tí ẹ bá ti se oúnjẹ yìí ni ẹ ti gbọdọ̀ jẹ gbogbo rẹ̀, ẹ kò gbọdọ̀ mú ninu ẹran rẹ̀ jáde, ẹ kò sì gbọdọ̀ fọ́ egungun rẹ̀. Gbogbo ìjọ eniyan Israẹli ni ó gbọdọ̀ ṣe ìrántí ọjọ́ yìí. Bí àlejò kan bá wọ̀ sí ilé yín, tí ó bá sì fẹ́ bá yín ṣe àjọ̀dún àjọ ìrékọjá, ó gbọdọ̀ kọ gbogbo àwọn ọkunrin inú ìdílé rẹ̀ ní ilà abẹ́, lẹ́yìn náà, ó lè ba yín ṣe àjọ̀dún náà, òun náà yóo dàbí olùgbé ilẹ̀ náà, ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí kò bá kọ ilà abẹ́ kò gbọdọ̀ jẹ ninu àjọ ìrékọjá náà. Ati ẹ̀yin, ati àlejò tí ń gbé ààrin yín, òfin kan ṣoṣo ni ó de gbogbo yín.” Gbogbo àwọn eniyan Israẹli bá ṣe bí àṣẹ tí OLUWA pa fún Mose ati Aaroni. Ní ọjọ́ yìí gan-an ni OLUWA mú àwọn ẹ̀yà Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. OLUWA sọ fún Mose pé, “Ya gbogbo àwọn àkọ́bí sí mímọ́ fún mi, ohunkohun tí ó bá ti jẹ́ àkọ́bí láàrin àwọn eniyan Israẹli, kì báà ṣe ti eniyan, tabi ti ẹranko, tèmi ni wọ́n.” Mose sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ ranti ọjọ́ òní tíí ṣe ọjọ́ tí ẹ jáde láti ilẹ̀ Ijipti, láti inú ìgbèkùn, nítorí pé pẹlu ipá ni OLUWA fi mu yín jáde kúrò níbẹ̀, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ burẹdi tí wọ́n fi ìwúkàrà sí. Òní ni ọjọ́ pé tí ẹ óo jáde kúrò ní Ijipti, ninu oṣù Abibu. Nígbà tí Ọlọrun bá mu yín wá sí ilẹ̀ àwọn ará Kenaani ati ti àwọn ará Hiti, ati ti àwọn ará Amori, ati ti àwọn ará Hifi, ati ti àwọn ará Jebusi, tí ó ti búra fún àwọn baba yín pé òun yóo fi fún yín, tí ó kún fún wàrà ati oyin, ẹ óo máa ṣe ìsìn yìí ninu oṣù yìí lọdọọdun. Ọjọ́ meje ni ẹ óo fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà, ní ọjọ́ keje ẹ óo pe àpèjọ kan fún OLUWA láti ṣe àjọ̀dún. Láàrin ọjọ́ meje tí ẹ óo fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà, a kò gbọdọ̀ rí burẹdi tí ó ní ìwúkàrà lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni ninu yín, kò sì gbọdọ̀ sí ìwúkàrà ní gbogbo agbègbè yín. Kí olukuluku wí fún ọmọ rẹ̀ ní ọjọ́ náà pé, ‘Nítorí ohun tí OLUWA ṣe fún mi, nígbà tí ó mú mi jáde láti ilẹ̀ Ijipti wá, ni mo fi ń ṣe ohun tí mò ń ṣe yìí.’ Kí ó jẹ́ àmì ní ọwọ́ rẹ, ati ohun ìrántí láàrin ojú rẹ, kí òfin OLUWA lè wà ní ẹnu rẹ, nítorí pé pẹlu ipá ni OLUWA fi mú ọ jáde láti ilẹ̀ Ijipti wá. Nítorí náà, ẹ máa ṣe ìrántí ìlànà yìí ní àkókò rẹ̀ ní ọdọọdún. “Nígbà tí OLUWA bá mu yín dé ilẹ̀ àwọn ará Kenaani, gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún ẹ̀yin ati àwọn baba yín, tí ó bá sì fún yín ní ilẹ̀ náà, gbogbo ohun tí ó bá ti jẹ́ àkọ́bí ni ẹ gbọdọ̀ yà sọ́tọ̀ fún OLUWA. Gbogbo àkọ́bí ẹran ọ̀sìn yín tí ó bá jẹ́ akọ, ti OLUWA ni. Ẹ gbọdọ̀ fi ọ̀dọ́ aguntan ra gbogbo àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yín pada, bí ẹ kò bá sì fẹ́ rà wọ́n pada, dandan ni pé kí ẹ lọ́ wọn lọ́rùn pa. Ẹ gbọdọ̀ ra gbogbo àkọ́bí yín tí wọ́n jẹ́ ọkunrin pada. Ní ọjọ́ iwájú bí àwọn ọmọkunrin yín bá bèèrè ìtumọ̀ ohun tí ẹ̀ ń ṣe lọ́wọ́ yín, ohun tí ẹ óo wí fún wọn ni pé, ‘Pẹlu ipá ni OLUWA fi mú wa jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, níbi tí a ti wà ní ìgbèkùn rí. Nítorí pé nígbà tí Farao ṣe orí kunkun, tí ó sì kọ̀, tí kò jẹ́ kí á lọ, OLUWA pa gbogbo àwọn àkọ́bí ilẹ̀ Ijipti, ti eniyan ati ti ẹranko. Ìdí nìyí tí mo fi ń fi àkọ́bí ẹran ọ̀sìn mi, tí ó bá jẹ́ akọ rúbọ sí OLUWA, tí mo sì fi ń ra àwọn àkọ́bí mi ọkunrin pada.’ Ẹ fi ṣe àmì sí ọwọ́ yín, ati ìgbàjú sí iwájú yín, nítorí pé pẹlu ipá ni OLUWA fi mú wa jáde ní ilẹ̀ Ijipti.” Nígbà tí Farao gbà pé kí àwọn ọmọ Israẹli máa lọ, Ọlọrun kò mú wọn gba ọ̀nà ilẹ̀ àwọn ará Filistia, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà ibẹ̀ yá, nítorí pé Ọlọrun rò ó ninu ara rẹ̀ pé, “Kí àwọn eniyan yìí má lọ yí ọkàn pada, bí àwọn kan bá gbógun tì wọ́n lójú ọ̀nà, kí wọ́n sì sá pada sí ilẹ̀ Ijipti.” Ṣugbọn Ọlọrun mú kí wọ́n gba ọ̀nà aṣálẹ̀, ní agbègbè Òkun Pupa, àwọn eniyan Israẹli sì jáde láti ilẹ̀ Ijipti pẹlu ìmúrasílẹ̀ ogun. Mose kó egungun Josẹfu lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n ń lọ, nítorí pé Josẹfu ti mú kí àwọn ọmọ Israẹli jẹ́jẹ̀ẹ́, ó ní, “Ọlọrun yóo gbà yín là, nígbà tí ó bá yá tí ẹ̀ bá ń lọ, ẹ kó egungun mi lọ́wọ́ lọ.” Wọ́n gbéra láti Sukotu, wọ́n pàgọ́ sí Etamu létí aṣálẹ̀. OLUWA sì ń lọ níwájú wọn ní ọ̀sán ninu ọ̀wọ̀n ìkùukùu láti máa fi ọ̀nà hàn wọ́n, ati ní òru, ninu ọ̀wọ̀n iná láti máa fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ kí wọ́n lè máa rìn ní ọ̀sán ati ní òru. Ọ̀wọ̀n ìkùukùu kò fi ìgbà kan kúrò níwájú àwọn eniyan náà ní ọ̀sán, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ọ̀wọ̀n iná ní òru. OLUWA bá rán Mose, ó ní, “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n yipada, kí wọ́n sì pàgọ́ siwaju Pi Hahirotu, láàrin Migidoli ati Òkun Pupa, níwájú Baali Sefoni; ẹ pàgọ́ yín siwaju rẹ̀ lẹ́bàá òkun. Nítorí Farao yóo wí pé, ‘Ilẹ̀ ti ká àwọn eniyan Israẹli mọ́, aṣálẹ̀ sì ti sé wọn mọ́.’ N óo tún mú kí ọkàn Farao le, yóo lépa yín, n óo sì gba ògo lórí Farao ati ogun rẹ̀, àwọn ará Ijipti yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” Àwọn eniyan Israẹli sì ṣe bí OLUWA ti wí. Nígbà tí wọ́n sọ fún Farao, ọba Ijipti, pé àwọn ọmọ Israẹli ti sálọ, èrò òun ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ nípa àwọn eniyan náà yipada. Wọ́n wí láàrin ara wọn pé, “Irú kí ni a ṣe yìí, tí a jẹ́ kí àwọn eniyan wọnyi lọ mọ́ wa lọ́wọ́, tí a kò jẹ́ kí wọ́n ṣì máa sìn wá?” Nítorí náà Farao ní kí wọ́n tọ́jú kẹ̀kẹ́ ogun òun, ó sì kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ. Ó ṣa ẹgbẹta (600) kẹ̀kẹ́ ogun tí ó dára, ati àwọn kẹ̀kẹ́ ogun ilẹ̀ Ijipti yòókù, ó sì yan àwọn olórí ogun tí yóo máa ṣe àkóso wọn. OLUWA mú ọkàn Farao, ọba Ijipti le, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa àwọn ọmọ Israẹli bí wọ́n ti ń lọ tìgboyà-tìgboyà. Àwọn ará Ijipti ń lé wọn lọ, pẹlu gbogbo ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun Farao, ati gbogbo àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀, ati gbogbo àwọn jagunjagun rẹ̀, wọ́n bá wọn níbi tí wọ́n pàgọ́ sí lẹ́bàá òkun, lẹ́bàá Pi Hahirotu ni òdìkejì Baali Sefoni. Nígbà tí Farao súnmọ́ àwọn ọmọ Israẹli, tí àwọn ọmọ Israẹli gbé ojú sókè tí wọ́n rí àwọn ará Ijipti tí wọn ń bọ̀ lẹ́yìn wọn; ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi. Wọ́n kígbe sí OLUWA; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sí Mose pé, “Ṣé kò sí ibojì ní Ijipti ni o fi kó wa kúrò láti wá kú sí ààrin aṣálẹ̀? Irú kí ni o ṣe sí wa yìí, tí o kó wa kúrò ní Ijipti? Ṣebí a sọ fún ọ ní Ijipti pé kí o fi wá sílẹ̀ kí á máa sin àwọn ará Ijipti tí à ń sìn, nítorí pé kì bá sàn kí á máa sin àwọn ará Ijipti ju kí á wá kú sinu aṣálẹ̀ lọ.” Mose bá dá àwọn eniyan náà lóhùn, ó ní, “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ dúró gbọningbọnin, kí ẹ wá máa wo ohun tí OLUWA yóo ṣe. Ẹ óo rí i bí yóo ṣe gbà yín là lónìí; nítorí pé àwọn ará Ijipti tí ẹ̀ ń wò yìí, ẹ kò tún ní rí wọn mọ́ laelae. OLUWA yóo jà fún yín, ẹ̀yin ẹ ṣá dúró jẹ́.” OLUWA wí fún Mose pé, “Kí ló dé tí o fi ń ké pè mí, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n tẹ̀síwájú. Gbé ọ̀pá rẹ sókè kí o na ọwọ́ sórí Òkun Pupa, kí ó sì pín in sí meji, kí àwọn eniyan Israẹli lè kọjá láàrin rẹ̀ lórí ìyàngbẹ ilẹ̀. N óo mú kí ọkàn àwọn ará Ijipti le, kí wọ́n sì tẹ̀lé àwọn ọmọ Israẹli wọ inú Òkun Pupa, n óo sì gba ògo lórí Farao ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀. Àwọn ará Ijipti yóo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA, nígbà tí mo bá gba ògo lórí Farao ati kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.” Angẹli Ọlọrun tí ó ti wà níwájú àwọn eniyan Israẹli bá bọ́ sẹ́yìn wọn, ọ̀wọ̀n ìkùukùu tí ó wà níwájú wọn náà bá pada sí ẹ̀yìn wọn. Ọ̀wọ̀n ìkùukùu náà sì wà láàrin àwọn ọmọ ogun Ijipti ati àwọn ọmọ ogun Israẹli, ìkùukùu náà ṣókùnkùn dudu títí tí gbogbo òru ọjọ́ náà fi kọjá, wọn kò sì súnmọ́ ara wọn. Mose na ọwọ́ rẹ̀ sórí Òkun Pupa; OLUWA bá mú kí afẹ́fẹ́ líle kan fẹ́ wá láti ìhà ìlà oòrùn ní gbogbo òru náà, afẹ́fẹ́ náà bi omi òkun sẹ́yìn, ó sì mú kí ààrin òkun náà di ìyàngbẹ ilẹ̀, omi rẹ̀ sì pín sí ọ̀nà meji. Àwọn ọmọ Israẹli bọ́ sí ààrin òkun náà lórí ìyàngbẹ ilẹ̀, omi òkun wá dàbí ògiri ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún ati ní ẹ̀gbẹ́ òsì wọn. Àwọn ará Ijipti lé wọn wọ inú òkun, tàwọn ti gbogbo ẹṣin Farao ati gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ati gbogbo ẹlẹ́ṣin rẹ̀. Nígbà tí ó di òwúrọ̀ kutukutu, OLUWA bojú wo ogun Ijipti láti òkè wá, ninu ọ̀wọ̀n iná, ati ọ̀wọ̀n ìkùukùu, ó sì dẹ́rùbà wọ́n. Ó mú kí ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun wọ́n há, tí ó fi jẹ́ pé àwọn kẹ̀kẹ́ náà wúwo rinrin. Àwọn ọmọ ogun Ijipti bá wí láàrin ara wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á sá fún àwọn ọmọ Israẹli, nítorí pé, OLUWA Ọlọrun ń bá wa jà nítorí wọn.” Ọlọrun bá sọ fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ sórí òkun pupa kí omi lè bo àwọn ará Ijipti ati kẹ̀kẹ́ ogun wọn, ati àwọn ẹlẹ́ṣin wọn mọ́lẹ̀.” Mose bá na ọwọ́ sórí òkun, òkun bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣàn tẹ́lẹ̀ nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ keji yóo fi mọ́; àwọn ará Ijipti gbìyànjú láti jáde, ṣugbọn OLUWA pa wọ́n run sinu òkun náà. Omi òkun pada sí ipò rẹ̀, ó sì bo gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun, ati àwọn ẹlẹ́ṣin, ati àwọn ọmọ ogun Farao tí wọ́n lépa àwọn ọmọ Israẹli wọ inú Òkun Pupa, ẹyọ kan kò sì yè ninu wọn. Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli rìn kọjá lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ ninu Òkun Pupa, omi rẹ̀ sì dàbí ògiri ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún ati ní ẹ̀gbẹ́ òsì wọn. Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe gba Israẹli lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti ní ọjọ́ náà, àwọn ọmọ Israẹli sì rí i bí àwọn ará Ijipti ti kú sí etí bèbè òkun. Àwọn ọmọ Israẹli rí ohun ńlá tí OLUWA ṣe sí àwọn ará Ijipti, wọ́n bẹ̀rù OLUWA, wọ́n sì gba OLUWA gbọ́, ati Mose, iranṣẹ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, Mose ati àwọn ọmọ Israẹli kọ orin yìí sí OLUWA, wọ́n ní: “N óo kọrin sí OLUWA, nítorí pé, ó ti ja àjàṣẹ́gun tí ó lógo. Àtẹṣin, àtẹni tí ń gùn ún ni ó dà sinu Òkun Pupa. OLUWA ni agbára ati orin mi, ó ti gbà mí là, òun ni Ọlọrun mi, n óo máa yìn ín. Òun ni Ọlọrun àwọn baba ńlá mi; n óo máa gbé e ga. Jagunjagun ni OLUWA, OLUWA sì ni orúkọ rẹ̀. Ó da kẹ̀kẹ́ ogun Farao ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sinu òkun, ó sì ri àwọn akọni ọmọ ogun rẹ̀ sinu Òkun Pupa. Ìkún omi bò wọ́n mọ́lẹ̀, wọ́n rilẹ̀ sinu ibú omi bí òkúta. Agbára ọwọ́ ọ̀tún rẹ pọ̀ jọjọ, OLUWA; OLUWA, ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ó fọ́ àwọn ọ̀tá túútúú. Ninu títóbi ọláńlá rẹ, o dojú àwọn ọ̀tá rẹ bolẹ̀, o fa ibinu yọ, ó sì jó wọn bí àgékù koríko. Èémí ihò imú rẹ mú kí omi gbájọ, ìkún omi dúró lóòró bí òkítì, ibú omi sì dì ní ìsàlẹ̀ òkun. Ọ̀tá wí pé, ‘N óo lé wọn, ọwọ́ mi yóo sì tẹ̀ wọ́n; n óo pín ìkógun, n óo sì tẹ́ ìfẹ́ ọkàn mi lọ́rùn lára wọn. N óo fa idà mi yọ, ọwọ́ mi ni n óo sì fi pa wọ́n run.’ Ṣugbọn o fẹ́ afẹ́fẹ́ lù wọ́n, òkun sì bò wọ́n mọ́lẹ̀, wọ́n rì bí òjé ninu ibú ńlá. “Ta ló dàbí rẹ OLUWA ninu àwọn oriṣa? Ta ló dàbí rẹ, ológo mímọ̀ jùlọ? Ẹlẹ́rù níyìn tíí ṣe ohun ìyanu. O na ọwọ́ ọ̀tún rẹ, ilẹ̀ sì yanu, ó gbé wọn mì. O ti fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ṣe amọ̀nà àwọn eniyan rẹ tí o rà pada, o ti fi agbára rẹ tọ́ wọn lọ sí ibùgbé mímọ́ rẹ. Àwọn eniyan ti gbọ́, wọ́n wárìrì, jìnnìjìnnì sì dà bo gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ Filistini. Ẹnu ya àwọn ìjòyè Edomu, ojora sì mú gbogbo àwọn olórí ní ilẹ̀ Moabu, gbogbo àwọn tí ń gbé Kenaani sì ti kú sára. Ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ati jìnnìjìnnì ti dà bò wọ́n, nítorí títóbi agbára rẹ, OLUWA, wọ́n dúró bí òkúta, títí tí àwọn eniyan rẹ fi kọjá lọ, àní àwọn tí o ti rà pada. O óo kó àwọn eniyan rẹ wọlé, o óo sì fi ìdí wọn múlẹ̀ lórí òkè mímọ́ rẹ, níbi tí ìwọ OLUWA ti pèsè fún ibùgbé rẹ, ibi mímọ́ rẹ tí ìwọ OLUWA ti fi ọwọ́ ara rẹ pèsè sílẹ̀. OLUWA yóo jọba títí lae ati laelae.” Nígbà tí àwọn ẹṣin Farao, ati àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ati àwọn ẹlẹ́ṣin wọ inú òkun, OLUWA mú kí omi òkun pada bò wọ́n mọ́lẹ̀, ṣugbọn àwọn eniyan Israẹli rìn lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ láàrin òkun. Nígbà náà ni Miriamu, wolii obinrin, tíí ṣe arabinrin Aaroni, gbé ìlù timbireli lọ́wọ́, gbogbo àwọn obinrin sì tẹ̀lé e, wọ́n ń lu timbireli, wọ́n sì ń jó. Miriamu bá dá orin fún wọn pé, “Ẹ kọrin sí OLUWA, nítorí tí ó ti ja àjàṣẹ́gun tí ó lógo, ó ti da ati ẹṣin ati àwọn ẹlẹ́ṣin sinu Òkun Pupa.” Mose bá bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn ọmọ Israẹli tẹ̀síwájú láti ibi Òkun Pupa, wọ́n ń lọ sí aṣálẹ̀ Ṣuri, ọjọ́ mẹta ni wọ́n fi rìn ninu aṣálẹ̀ láìrí omi. Nígbà tí wọ́n dé Mara, wọn kò lè mu omi tí wọ́n rí níbẹ̀, nítorí pé ó korò. Nítorí náà, wọ́n sọ orúkọ ibẹ̀ ní Mara, ìtumọ̀ èyí tíí ṣe ìkorò. Ni àwọn eniyan náà bá bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Mose, wọ́n ní, “Kí ni a óo mu?” Mose bá kígbe sí OLUWA, OLUWA fi igi kan hàn án. Mose ju igi náà sinu omi, omi náà sì di dídùn. Ibẹ̀ ni OLUWA ti fún wọn ní ìlànà ati òfin, ó sì dán wọn wò, ó ní, “Bí ẹ bá farabalẹ̀ gbọ́ ohùn èmi OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú mi, tí ẹ pa gbogbo òfin mi mọ́, tí ẹ sì tẹ̀lé gbogbo ìlànà mi, èmi OLUWA kò ní fi èyíkéyìí ninu àwọn àrùn tí mo fi ṣe àwọn ará Ijipti ṣe yín, nítorí pé, èmi ni OLUWA, olùwòsàn yín.” Lẹ́yìn náà ni wọ́n dé Elimu, níbi tí orísun omi mejila ati aadọrin igi ọ̀pẹ wà, wọ́n sì pàgọ́ sẹ́bàá àwọn orísun omi náà. Nígbà tí ó yá, gbogbo ìjọ eniyan Israẹli jáde kúrò ní Elimu, wọ́n lọ sí aṣálẹ̀ Sini tí ó wà ní ààrin Elimu ati Sinai, ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù keji tí wọ́n jáde kúrò ní Ijipti ni wọ́n dé aṣálẹ̀ náà. Gbogbo ìjọ eniyan Israẹli bá bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Mose ati Aaroni ninu aṣálẹ̀, wọ́n ń wí pé, “Ìbá sàn kí OLUWA pa wá sí ilẹ̀ Ijipti, níbi tí olukuluku wa ti jókòó ti ìsaasùn ọbẹ̀ ẹran, tí a sì ń jẹ oúnjẹ àjẹyó, ju bí ẹ ti kó wa wá sí ààrin aṣálẹ̀ yìí lọ, láti fi ebi pa gbogbo wa kú.” OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Wò ó, n óo rọ̀jò oúnjẹ fún yín láti ọ̀run. Kí àwọn eniyan máa jáde lọ ní ojoojumọ, kí wọ́n sì máa kó ìwọ̀nba ohun tí wọn yóo jẹ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. N óo fi èyí dán wọn wò, kí n fi mọ̀ bóyá wọn yóo máa tẹ̀lé òfin mi tabi wọn kò ní tẹ̀lé e. Nígbà tí ó bá di ọjọ́ kẹfa, kí wọ́n kó oúnjẹ wálé kí ó tó ìlọ́po meji èyí tí wọn ń kó ní ojoojumọ.” Mose ati Aaroni bá sọ fún gbogbo àwọn eniyan Israẹli pé, “Ní ìrọ̀lẹ́ òní ni ẹ óo mọ̀ pé OLUWA ló mú yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti. Nígbà tí ó bá di òwúrọ̀ ọ̀la, ẹ óo rí ògo OLUWA, nítorí ó ti gbọ́ kíkùn tí ẹ̀ ń kùn sí i. Kí ni àwa yìí jẹ́, tí ẹ óo fi máa kùn sí wa?” Mose ní, “OLUWA tìkararẹ̀ ni yóo fún yín ní ẹran ní ìrọ̀lẹ́, ati burẹdi ní òwúrọ̀. Ẹ óo jẹ àjẹyó, nítorí pé ó ti gbọ́ gbogbo kíkùn tí ẹ̀ ń kùn sí i; nítorí pé kí ni àwa yìí jẹ́? Gbogbo kíkùn tí ẹ̀ ń kùn, àwa kọ́ ni ẹ̀ ń kùn sí, OLUWA gan-an ni ẹ̀ ń kùn sí.” Mose sọ fún Aaroni pé, “Sọ fún gbogbo ìjọ eniyan Israẹli pé, kí wọ́n súnmọ́ tòsí ọ̀dọ̀ OLUWA, nítorí pé ó ti gbọ́ gbogbo kíkùn wọn.” Bí Aaroni ti ń bá gbogbo ìjọ eniyan Israẹli sọ̀rọ̀, wọ́n wo apá aṣálẹ̀, wọ́n sì rí i pé ògo OLUWA hàn ninu ìkùukùu. OLUWA bá wí fún Mose pé, “Mo ti gbọ́ kíkùn tí àwọn ọmọ Israẹli ń kùn, wí fún wọn pé, ‘Ní ìrọ̀lẹ́, ẹ óo máa jẹ ẹran, ní òwúrọ̀, ẹ óo máa jẹ burẹdi ní àjẹyó. Nígbà náà ni ẹ óo tó mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.’ ” Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, àwọn ẹyẹ àparò fò dé, wọ́n sì bo gbogbo àgọ́ náà; nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ keji mọ́, ìrì sẹ̀ bo gbogbo àgọ́ náà. Nígbà tí ìrì náà kásẹ̀ nílẹ̀, wọ́n rí i tí kinní funfun kan tí ó dàbí ìrì dídì bo ilẹ̀ ní gbogbo aṣálẹ̀ náà. Nígbà tí àwọn eniyan Israẹli rí i, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bi ara wọn léèrè pé, “Kí nìyí?” Nítorí pé, wọn kò mọ ohun tíí ṣe. Mose bá dá wọn lóhùn pé, “Oúnjẹ tí OLUWA fún yín láti jẹ ni. Àṣẹ tí OLUWA pa ni pé, ‘Kí olukuluku yín kó ìwọ̀nba tí ó lè jẹ tán, kí ẹ kó ìwọ̀n Omeri kan fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu àgọ́ yín.’ ” Àwọn eniyan Israẹli sì ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn mìíràn kó ju ohun tí ó yẹ kí wọ́n kó, àwọn mìíràn kò sì kó tó. Ṣugbọn nígbà tí wọn fi ìwọ̀n Omeri wọ̀n ọ́n, àwọn tí wọ́n kó pupọ jù rí i pé, ohun tí wọ́n kó, kò lé nǹkankan; àwọn tí wọn kò sì kó pupọ rí i pé ohun tí wọ́n kó tó wọn; olukuluku kó ìwọ̀n tí ó lè jẹ. Mose wí fún wọn pé, “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe ṣẹ́ ohunkohun kù di òwúrọ̀ ọjọ́ keji.” Ṣugbọn wọn kò gbọ́rọ̀ sí Mose lẹ́nu; àwọn mìíràn ṣẹ́ ẹ kù di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ keji mọ́, ohun tí wọ́n ṣẹ́kù ti bẹ̀rẹ̀ sí yọ ìdin, ó sì ń rùn, Mose bá bínú sí wọn. Ní àràárọ̀ ni olukuluku máa ń kó ohun tí ó bá lè jẹ tán, nígbà tí oòrùn bá gòkè, gbogbo èyí tí ó bá wà nílẹ̀ yóo sì yọ́ dànù. Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹfa, wọ́n kó ìlọ́po meji, olukuluku kó ìwọ̀n Omeri meji meji. Nígbà tí àwọn àgbààgbà Israẹli lọ sọ fún Mose, ó wí fún wọn pé, “Ohun tí OLUWA wí nìyí, ‘Ọ̀la ni ọjọ́ ìsinmi tí ó ní ọ̀wọ̀, ọjọ́ ìsinmi mímọ́ fún OLUWA. Ẹ dín ohun tí ẹ bá fẹ́ dín, kí ẹ sì se ohun tí ẹ bá fẹ́ sè, ohun tí ó bá ṣẹ́kù, ẹ fi pamọ́ títí di òwúrọ̀ ọ̀la.’ ” Wọ́n bá fi ìyókù pamọ́ títí di òwúrọ̀ gẹ́gẹ́ bí Mose ti sọ fún wọn; kò sì rùn, bẹ́ẹ̀ ni kò yọ ìdin. Mose wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ èyí lónìí, nítorí pé òní ni ọjọ́ ìsinmi OLUWA, ẹ kò ní rí kó rárá ní òní. Ọjọ́ mẹfa ni ẹ óo fi máa rí oúnjẹ kó, ṣugbọn ní ọjọ́ keje tíí ṣe ọjọ́ ìsinmi, kò ní sí níbẹ̀ rárá.” Ní ọjọ́ keje, àwọn mìíràn ninu àwọn eniyan náà jáde láti lọ kó oúnjẹ, ṣugbọn wọn kò rí ohunkohun. OLUWA bá wí fún Mose pé, “Yóo ti pẹ́ tó, tí ẹ óo fi kọ̀ láti pa àṣẹ ati òfin mi mọ́. Ẹ wò ó! OLUWA ti fún yín ní ọjọ́ ìsinmi, nítorí náà ni ó fi jẹ́ pé, ní ọjọ́ kẹfa ó fún yín ní oúnjẹ fún ọjọ́ meji, kí olukuluku lè dúró sí ààyè rẹ̀, kí ẹnikẹ́ni má ṣe jáde ní ilé rẹ̀ ní ọjọ́ keje.” Àwọn eniyan náà bá sinmi ní ọjọ́ keje. Àwọn eniyan Israẹli pe orúkọ oúnjẹ náà ní mana, ó rí rínbíntín-rínbíntín, ó dàbí èso igi korianda, ó funfun, ó sì dùn lẹ́nu bíi burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí wọ́n fi oyin ṣe. Mose wí fún wọn pé, “Àṣẹ tí OLUWA pa nìyí: ‘Ẹ fi ìwọ̀n omeri kan pamọ́ láti ìrandíran yín, kí àwọn ọmọ yín lè rí irú oúnjẹ tí mo fi bọ́ yín ninu aṣálẹ̀ nígbà tí mo ko yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti wá.’ ” Mose bá sọ fún Aaroni pé, “Mú ìkòkò kan kí o fi ìwọ̀n omeri mana kan sinu rẹ̀, kí o gbé e kalẹ̀ níwájú OLUWA, kí ẹ pa á mọ́ láti ìrandíran yín.” Aaroni bá gbé e kalẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA ti pa fún Mose. Àwọn eniyan Israẹli jẹ mana náà fún ogoji ọdún, títí wọ́n fi dé ilẹ̀ tí wọ́n lè máa gbé, òun ni wọ́n jẹ títí tí wọ́n fi dé etí ilẹ̀ Kenaani. Ìwọ̀n omeri kan jẹ́ ìdámẹ́wàá ìwọ̀n efa kan. Gbogbo ìjọ eniyan Israẹli gbéra láti aṣálẹ̀ Sini, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lọ láti ibùsọ̀ kan dé ekeji, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún wọn. Wọ́n pàgọ́ sí Refidimu, ṣugbọn kò sí omi fún wọn láti mu. Wọ́n bá ka ẹ̀sùn sí Mose lẹ́sẹ̀, wọ́n ní, “Fún wa ní omi tí a óo mu.” Mose dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ka ẹ̀sùn sí mi lẹ́sẹ̀? Kí ló dé tí ẹ sì fi ń dán OLUWA wò?” Ṣugbọn òùngbẹ ń gbẹ àwọn eniyan náà, wọ́n fẹ́ mu omi, wọ́n bá ń kùn sí Mose, wọ́n wí pé, “Kí ló dé tí o fi kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti, láti fi òùngbẹ pa àwa ati àwọn ọmọ wa, ati àwọn ẹran ọ̀sìn wa?” Mose bá tún kígbe pe OLUWA, ó ní, “Kí ni n óo ṣe sí àwọn eniyan wọnyi, wọ́n ti múra láti sọ mí lókùúta.” OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Mú ninu àwọn àgbààgbà ilẹ̀ Israẹli lọ́wọ́, kí ẹ jọ la ààrin àwọn eniyan náà kọjá, kí o sì mú ọ̀pá tí o fi lu odò Naili lọ́wọ́, bí o bá ti ń lọ. N óo dúró níwájú rẹ lórí àpáta ní òkè Horebu. Nígbà tí o bá fi ọ̀pá lu àpáta náà, omi yóo ti inú rẹ̀ jáde, àwọn eniyan náà yóo sì mu ún.” Mose bá ṣe bẹ́ẹ̀ níwájú gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli. Ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Masa ati Meriba, nítorí ìwà ìka-ẹ̀sùn-síni-lẹ́sẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli hù, ati nítorí dídán tí wọn dán OLUWA wò, wọ́n ní, “Ṣé OLUWA tún wà láàrin wa ni tabi kò sí mọ́?” Lẹ́yìn èyí ni àwọn ará Amaleki wá, wọ́n sì bá àwọn ọmọ Israẹli jagun ní Refidimu. Mose bá wí fún Joṣua pé, “Yan àwọn akọni ọkunrin láàrin yín kí o sì jáde lọ láti bá àwọn ará Amaleki jagun lọ́la, n óo dúró ní orí òkè pẹlu ọ̀pá Ọlọrun ní ọwọ́ mi.” Joṣua ṣe bí Mose ti pàṣẹ fún un, ó bá àwọn ará Amaleki jagun. Mose ati Aaroni ati Huri bá gun orí òkè lọ. Nígbà tí Mose bá gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, àwọn ọmọ Israẹli a máa borí àwọn ará Amaleki, nígbà tí ó bá sì rẹ ọwọ́ sílẹ̀, àwọn ará Amaleki a máa borí àwọn ọmọ Israẹli. Nígbà tí ó yá, apá bẹ̀rẹ̀ sí ro Mose, wọ́n gbé òkúta kan fún un láti fi jókòó, ó sì jókòó lórí rẹ̀. Aaroni ati Huri bá a gbé apá rẹ̀ sókè, ẹnìkan gbé apá ọ̀tún, ẹnìkejì sì gbé apá òsì. Apá rẹ̀ wà lókè títí tí oòrùn fi ń lọ wọ̀. Joṣua bá fi idà pa Amaleki ati àwọn eniyan rẹ̀ ní ìpakúpa. OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Kọ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sinu ìwé kan fún ìrántí, sì kà á sí etígbọ̀ọ́ Joṣua, pé n óo pa Amaleki rẹ́ patapata, a kò sì ní ranti rẹ̀ mọ́ láyé.” Mose bá tẹ́ pẹpẹ kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní “OLUWA ni àsíá mi.” Ó ní, “Gbé àsíá OLUWA sókè! OLUWA yóo máa bá ìrandíran àwọn ará Amaleki jà títí lae.” Jẹtiro, alufaa àwọn ará Midiani, baba iyawo Mose, gbọ́ gbogbo ohun tí Ọlọrun ti ṣe fún Mose ati fún Israẹli, àwọn eniyan rẹ̀, ati bí ó ti mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. Jẹtiro, baba iyawo Mose mú Sipora aya Mose, lẹ́yìn tí Mose ti dá a pada sọ́dọ̀ baba rẹ̀ tẹ́lẹ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin mejeeji. Orúkọ ọmọ rẹ̀ kinni ni Geriṣomu, (ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, “Mo ti jẹ́ àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì.”) Orúkọ ọmọ keji ni Elieseri, (ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, “Ọlọrun baba mi ni olùrànlọ́wọ́ mi, òun ni ó sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ idà Farao.”) Jẹtiro, baba iyawo Mose, mú iyawo Mose, ati àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji tọ̀ ọ́ wá ní aṣálẹ̀, níbi tí wọ́n pàgọ́ sí níbi òkè Ọlọrun. Nígbà tí wọ́n sọ fún Mose pé Jẹtiro, baba iyawo rẹ̀, ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹlu iyawo rẹ̀ ati àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji, Mose lọ pàdé wọn, ó wólẹ̀ níwájú Jẹtiro, ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu, wọ́n bèèrè alaafia ara wọn, wọ́n sì wọ inú àgọ́ lọ. Gbogbo ohun tí Ọlọrun ṣe sí Farao ati sí àwọn ará Ijipti nítorí àwọn ọmọ Israẹli ni Mose ròyìn fún baba iyawo rẹ̀. Ó sọ gbogbo ìṣòro tí wọ́n rí lójú ọ̀nà, ati bí OLUWA ti kó wọn yọ. Jẹtiro sì bá wọn yọ̀ nítorí gbogbo oore tí OLUWA ti ṣe fún àwọn ọmọ Israẹli, nítorí gbígbà tí ó gbà wọ́n kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti. Jẹtiro dáhùn, ó ní, “Ẹni ìyìn ni OLUWA, tí ó gbà yín kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti ati lọ́wọ́ Farao. Mo mọ̀ nisinsinyii pé OLUWA ju gbogbo àwọn oriṣa lọ, nítorí pé ó ti gba àwọn eniyan náà lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti, nígbà tí àwọn ará Ijipti ń lò wọ́n ní ìlò àbùkù ati ẹ̀gàn.” Jẹtiro bá rú ẹbọ sísun sí Ọlọrun. Aaroni ati àwọn àgbààgbà Israẹli sì wá sọ́dọ̀ Jẹtiro, láti bá a jẹun níwájú Ọlọrun. Ní ọjọ́ keji, Mose jókòó, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìdájọ́ fún àwọn ọmọ Israẹli, àwọn eniyan wà lọ́dọ̀ rẹ̀ láti òwúrọ̀ títí di àṣáálẹ́. Nígbà tí baba iyawo Mose rí gbogbo ohun tí Mose ń ṣe fún àwọn eniyan, ó pè é, ó ní, “Kí ni gbogbo ohun tí ò ń ṣe fún àwọn eniyan wọnyi? Kí ló dé tí o fi wà lórí àga ìdájọ́ láti òwúrọ̀ títí di àṣáálẹ́, tí àwọn eniyan ń kó ẹjọ́ wá bá ìwọ nìkan?” Mose dáhùn pé, “Ọ̀dọ̀ mi ni àwọn eniyan náà ti máa ń bèèrè ohun tí Ọlọrun fẹ́ kí wọ́n ṣe. Nígbà tí èdè-àìyedè bá wà láàrin àwọn aládùúgbò meji, èmi ni mo máa ń parí rẹ̀ fún wọn. Èmi náà ni mo sì máa ń sọ òfin Ọlọrun, ati àwọn ìpinnu rẹ̀ fún wọn.” Baba iyawo rẹ̀ bá bá a wí pé, “Ohun tí ò ń ṣe yìí kò dára. Àtìwọ àtàwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ, ẹ óo pa ara yín; ohun tí ò ń ṣe yìí ti pọ̀ jù fún ọ, o kò lè dá a ṣe. Gbọ́ ohun tí n óo sọ fún ọ yìí, ìmọ̀ràn ni mo fẹ́ gbà ọ́, Ọlọrun yóo sì wà pẹlu rẹ. Ó dára kí o máa ṣe aṣojú àwọn eniyan náà níwájú Ọlọrun, kí o sì máa bá wọn kó ẹ̀dùn ọkàn wọn tọ Ọlọrun lọ; ó sì dára bákan náà pẹlu kí o máa kọ́ wọn ní òfin ati ìlànà, kí o sì máa fi ọ̀nà tí wọn yóo tọ̀ hàn wọ́n, ati ohun tí wọ́n gbọdọ̀ máa ṣe. Ohun tí ó yẹ kí o ṣe nìyí, yan àwọn ọkunrin tí wọ́n lè jẹ́ alákòóso, àwọn tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọrun, tí wọ́n ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, tí wọ́n sì kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀; fi wọ́n ṣe alákòóso àwọn eniyan wọnyi, fi àwọn kan ṣe alákòóso lórí ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, àwọn kan lórí ọgọọgọrun-un eniyan, àwọn kan lórí araadọta, ati àwọn mìíràn lórí eniyan mẹ́wàá mẹ́wàá. Jẹ́ kí wọn máa ṣe onídàájọ́ fún àwọn eniyan náà nígbà gbogbo; àwọn ọ̀rọ̀ tí ó bá jẹ́ pataki pataki nìkan ni wọn yóo máa kó wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, kí wọ́n máa parí àwọn ẹjọ́ kéékèèké láàrin ara wọn. Èyí yóo mú kí ó rọ̀ ọ́ lọ́rùn, wọn yóo sì máa bá ọ gbé ninu ẹrù náà. Bí Ọlọrun bá gbà fún ọ láti ṣe bẹ́ẹ̀, tí o sì ṣe é, ẹ̀mí rẹ yóo gùn, gbogbo àwọn eniyan wọnyi náà yóo sì pada sí ilé wọn ní alaafia.” Mose gba ọ̀rọ̀ tí baba iyawo rẹ̀ sọ, ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn tí ó fún un. Mose yan àwọn ọkunrin tí wọ́n lè ṣe alákòóso ninu àwọn eniyan Israẹli, ó fi wọ́n ṣe olórí àwọn eniyan náà, àwọn kan jẹ́ alákòóso fún ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, àwọn mìíràn, fún ọgọọgọrun-un eniyan, àwọn mìíràn, fún araadọta, àwọn mìíràn fún eniyan mẹ́wàá mẹ́wàá. Wọ́n ń ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan náà nígbà gbogbo; àwọn ọ̀rọ̀ tí ó bá fẹ́ díjú nìkan ni wọ́n ń kó tọ Mose lọ, wọ́n ń yanjú àwọn ọ̀rọ̀ kéékèèké láàrin ara wọn. Mose gbà fún baba iyawo rẹ̀ pé kí ó máa pada lọ sí ìlú rẹ̀, baba iyawo rẹ̀ gbéra, ó sì pada sí orílẹ̀-èdè rẹ̀. Ní oṣù kẹta tí àwọn eniyan Israẹli kúrò ní ilẹ̀ Ijipti ni wọ́n dé aṣálẹ̀ Sinai. Refidimu ni wọ́n ti gbéra wá sí aṣálẹ̀ Sinai. Nígbà tí wọ́n dé aṣálẹ̀ yìí, wọ́n pàgọ́ wọn siwaju òkè Sinai. Mose bá gòkè tọ Ọlọrun lọ. OLUWA pè é láti orí òkè náà, ó ní, “Ohun tí mo fẹ́ kí o sọ fún àwọn ọmọ Israẹli nìyí, ‘Ṣé ẹ rí ohun tí èmi OLUWA fi ojú àwọn ará Ijipti rí, ati bí mo ti fi ẹ̀yìn pọ̀n yín títí tí mo fi kó yín wá sí ọ̀dọ̀ mi níhìn-ín? Nítorí náà, bí ẹ bá gbọ́ tèmi, tí ẹ sì pa majẹmu mi mọ́ ẹ óo jẹ́ tèmi láàrin gbogbo eniyan, nítorí pé tèmi ni gbogbo ayé yìí patapata; ẹ óo di ìran alufaa ati orílẹ̀-èdè mímọ́ fún mi.’ Bẹ́ẹ̀ ni kí o sọ fún àwọn ọmọ Israẹli.” Mose bá pada wá, ó pe àwọn àgbààgbà Israẹli jọ, ó sì sọ gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún un fún wọn. Gbogbo àwọn eniyan náà bá pa ohùn pọ̀, wọ́n ní, “Gbogbo ohun tí OLUWA wí ni a óo ṣe.” Mose bá lọ sọ ohun tí àwọn eniyan náà wí fún OLUWA. OLUWA sọ fún Mose pé, “Mò ń tọ̀ ọ́ bọ̀ ninu ìkùukùu tí yóo bo gbogbo ilẹ̀, kí àwọn eniyan náà lè gbọ́ nígbà tí mo bá ń bá ọ sọ̀rọ̀, kí wọ́n sì lè gbà ọ́ gbọ́ títí lae.” Mose sọ ohun tí àwọn eniyan náà wí fún OLUWA. OLUWA bá dá Mose lóhùn, ó ní, “Tọ àwọn eniyan náà lọ kí o sì yà wọ́n sí mímọ́ lónìí ati lọ́la. Sọ fún wọn pé kí wọ́n fọ aṣọ wọn, kí wọ́n wà ní ìmúrasílẹ̀ ní ọjọ́ kẹta, nítorí pé ní ọjọ́ kẹta yìí ni èmi OLUWA óo sọ̀kalẹ̀ sórí òkè Sinai, lójú gbogbo wọn. Pààlà yípo òkè náà fún wọn, kí o sì kìlọ̀ fún wọn pé, kí wọ́n ṣọ́ra, kí wọ́n má ṣe gun òkè yìí, tabi fi ọwọ́ kan ẹsẹ̀ òkè náà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkè yìí, pípa ni n óo pa á. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kàn án, òkúta ni kí wọ́n sọ pa á tabi kí wọ́n ta á ní ọfà; kì báà ṣe ẹranko tabi eniyan, dandan ni kí ó kú. Nígbà tí fèrè bá dún, tí dídún rẹ̀ pẹ́, kí wọn wá sí ẹ̀bá òkè náà.” Mose bá sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, ó tọ àwọn eniyan náà lọ, ó yà wọ́n sí mímọ́, wọ́n sì fọ aṣọ wọn. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ múrasílẹ̀ di ọ̀tunla, ẹ má ṣe súnmọ́ obinrin láti bá a lòpọ̀.” Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kẹta, ààrá bẹ̀rẹ̀ sí sán, bẹ́ẹ̀ ni mànàmáná ń kọ, ìkùukùu sì bo òkè náà mọ́lẹ̀, fèrè kan dún tóbẹ́ẹ̀ tí gbogbo eniyan tí wọ́n wà ninu àgọ́ wárìrì. Mose bá kó àwọn eniyan náà jáde láti pàdé Ọlọrun, wọ́n sì dúró ní ẹsẹ̀ òkè. Èéfín bo gbogbo òkè Sinai mọ́lẹ̀, nítorí pé ninu iná ni OLUWA ti sọ̀kalẹ̀ sórí rẹ̀, ọ̀wọ̀n èéfín rẹ̀ sì gòkè lọ bí ọ̀wọ̀n èéfín iná ìléru ńlá, gbogbo òkè náà sì mì tìtì. Bí fèrè ti ń dún kíkankíkan tí dídún rẹ̀ sì ń gòkè sí i, bẹ́ẹ̀ ni Mose ń sọ̀rọ̀, Ọlọrun sì ń fi ààrá dá a lóhùn. OLUWA sọ̀kalẹ̀ sórí òkè Sinai, ó dúró ní ṣóńṣó òkè náà, ó pe Mose sọ́dọ̀, Mose sì gòkè tọ̀ ọ́ lọ. OLUWA sọ fún un pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ, kí o sì kìlọ̀ fún àwọn eniyan náà, kí wọ́n má baà rọ́ wọ ibi tí OLUWA wà láti wò ó, kí ọpọlọpọ wọn má baà parun. Ati pé, kí àwọn alufaa tí yóo súnmọ́ ibi tí OLUWA wà, ya ara wọn sí mímọ́, kí n má baà jẹ wọ́n níyà.” Mose bá dá OLUWA lóhùn pé, “OLUWA, àwọn eniyan wọnyi kò lè gun òkè Sinai wá, nítorí pé ìwọ náà ni o pàṣẹ pé kí á pààlà yí òkè náà po, kí á sì yà á sí mímọ́.” OLUWA sì wí fún un pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ, kí o mú Aaroni gòkè wá, ṣugbọn má ṣe jẹ́ kí àwọn alufaa ati àwọn eniyan náà rọ́ wá sórí òkè níbi tí mo wà, kí n má baà jẹ wọ́n níyà.” Mose bá sọ̀kalẹ̀ lọ bá àwọn eniyan náà, ó sì jíṣẹ́ fún wọn. Ọlọrun sì sọ ọ̀rọ̀ wọnyii, ó ní, “Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, ní oko ẹrú tí ẹ wà: “O kò gbọdọ̀ ní ọlọrun mìíràn lẹ́yìn mi. “O kò gbọdọ̀ yá èrekére fún ara rẹ, kì báà ṣe àwòrán ohun tí ó wà ní òkè ọ̀run, tabi ti ohun tí ó wà ní orí ilẹ̀, tabi ti ohun tí ó wà ninu omi ní abẹ́ ilẹ̀. O kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ bọ wọ́n; nítorí Ọlọrun tí í máa ń jowú ni èmi OLUWA Ọlọrun rẹ. Èmi a máa fi ẹ̀ṣẹ̀ baba bi ọmọ, títí dé ìran kẹta ati ẹkẹrin lára àwọn tí wọ́n kórìíra mi. Ṣugbọn èmi a máa fi ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ hàn sí ẹgbẹẹgbẹrun àwọn tí wọ́n fẹ́ mi, tí wọ́n sì ń pa òfin mi mọ́. “O kò gbọdọ̀ pe orúkọ OLUWA Ọlọrun rẹ lásán, nítorí pé, èmi OLUWA yóo dá ẹnikẹ́ni tí ó bá pe orúkọ mi lásán lẹ́bi. “Ranti ọjọ́ ìsinmi kí o sì yà á sí mímọ́. Ọjọ́ mẹfa ni kí olukuluku máa fi ṣiṣẹ́, kí ó sì máa fi parí ohun tí ó bá níláti ṣe. Ṣugbọn ọjọ́ keje jẹ́ ọjọ́ ìsinmi tí olukuluku níláti yà sọ́tọ̀ fún èmi OLUWA Ọlọrun rẹ̀. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà; olukuluku yín ati ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin, ati ẹrú rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin, ati ẹran ọ̀sìn rẹ̀, ati àlejò tí ó wà ninu ilé rẹ̀. Nítorí pé, ọjọ́ mẹfa ni èmi OLUWA fi dá ọ̀run ati ayé, ati òkun, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn; mo sì sinmi ní ọjọ́ keje. Nítorí náà ni mo ṣe bukun ọjọ́ ìsinmi náà, tí mo sì yà á sí mímọ́. “Bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ, kí ẹ̀mí rẹ lè gùn lórí ilẹ̀ tí èmi OLUWA Ọlọrun rẹ fi fún ọ. “O kò gbọdọ̀ paniyan. “O kò gbọdọ̀ ṣe panṣaga. “O kò gbọdọ̀ jalè. “O kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké sí ọmọnikeji rẹ. “O kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí ilé ọmọnikeji rẹ, tabi sí aya rẹ̀ tabi sí iranṣẹ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin, tabi sí akọ mààlúù rẹ̀, tabi sí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, tabi sí ohunkohun tí ó jẹ́ ti ọmọnikeji rẹ.” Nígbà tí àwọn eniyan náà gbọ́ bí ààrá ti ń sán, tí wọ́n rí i bí mànàmáná ti ń kọ, tí wọ́n gbọ́ dídún ìró fèrè, tí wọ́n rí i tí òkè ń rú èéfín, ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì wárìrì. Wọ́n dúró lókèèrè, wọ́n sì wí fún Mose pé, “Ìwọ ni kí o máa bá wa sọ̀rọ̀, a óo máa gbọ́; má jẹ́ kí Ọlọrun bá wa sọ̀rọ̀ mọ́, kí a má baà kú.” Mose bá dá àwọn eniyan náà lóhùn pé, “Ẹ má jẹ́ kí ẹ̀rù bà yín, Ọlọrun wá dán yín wò ni, kí ẹ lè máa bẹ̀rù rẹ̀, kí ẹ má baà dẹ́ṣẹ̀.” Àwọn eniyan náà dúró lókèèrè, bí Mose tí ń súnmọ́ òkùnkùn biribiri tí ó ṣú bo ibi tí Ọlọrun wà. OLUWA ní kí Mose sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, “Ẹ ti rí i fúnra yín pé mo ba yín sọ̀rọ̀ láti ọ̀run wá. Ẹ kò gbọdọ̀ fi wúrà tabi fadaka yá ère láti máa bọ, àfi èmi nìkan ni kí ẹ máa sìn. Yẹ̀ẹ̀pẹ̀ ni kí ẹ fi tẹ́ pẹpẹ fún mi, kí ẹ sì máa rú ẹbọ sísun yín ati ẹbọ alaafia yín lórí rẹ̀, kì báà ṣe aguntan tabi mààlúù. Níbikíbi tí mo bá pa láṣẹ pé kí ẹ ti sìn mí, n óo tọ̀ yín wá, n óo sì súre fún yín níbẹ̀. Bí ẹ bá fi òkúta tẹ́ pẹpẹ fún mi, ẹ má lo òkúta tí wọ́n bá gbẹ́, nítorí pé bí ẹ bá fi ohun èlò yín ṣiṣẹ́ lára òkúta náà, ẹ ti sọ ọ́ di aláìmọ́. Ẹ kò gbọdọ̀ tẹ́ pẹpẹ tí ẹ óo máa fi àtẹ̀gùn gùn, kí wọ́n má baà máa rí ìhòòhò yín lórí rẹ̀. “Àwọn òfin tí o gbọdọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli nìwọ̀nyí: Bí ẹnikẹ́ni bá ra Heberu kan lẹ́rú, ọdún mẹfa ni ẹrú náà óo fi sìn ín, ní ọdún keje, ó níláti dá a sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́ láìgba ohunkohun lọ́wọ́ rẹ̀. Bí ó bá jẹ́ pé òun nìkan ni ó rà, òun nìkan ni òfin dá sílẹ̀, ṣugbọn bí ẹrú náà bá mú aya rẹ̀ lọ́wọ́ wá, bí ó bá ti ń dá a sílẹ̀, ó gbọdọ̀ dá aya rẹ̀ sílẹ̀ pẹlu. Bí olówó rẹ̀ bá fẹ́ aya fún un, tí aya náà sì bímọ fún un, lọkunrin ati lobinrin, olówó rẹ̀ ni ó ni aya ati àwọn ọmọ patapata, òun nìkan ni òfin dá sílẹ̀. Ṣugbọn bí ẹrú náà bá fúnra rẹ̀ wí ní gbangba pé òun fẹ́ràn olówó òun, ati aya òun, ati àwọn ọmọ òun, nítorí náà òun kò ní gba ìdásílẹ̀, kí òun má baà fi wọ́n sílẹ̀, olówó rẹ̀ yóo mú un wá siwaju Ọlọrun, ní ibi ìlẹ̀kùn àgọ́ tabi òpó ìlẹ̀kùn, olówó rẹ̀ yóo fi òòlù lu ihò sí etí rẹ̀, ẹrú náà yóo sì di tirẹ̀ títí ayé. “Bí ẹnìkan bá ta ọmọ rẹ̀ obinrin lẹ́rú, ẹrubinrin yìí kò ní jáde bí ẹrukunrin. Bí ẹrubinrin yìí kò bá wù olówó rẹ̀ láti fi ṣe aya, ó níláti dá a pada fún baba rẹ̀, baba rẹ̀ yóo sì rà á pada. Olówó rẹ̀ kò ní ẹ̀tọ́ láti tà á fún àjèjì nítorí pé òun ló kọ̀ tí kò ṣe ẹ̀tọ́ fún un. Bí ó bá fẹ́ ẹ sọ́nà fún ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ó gbọdọ̀ ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ gan-an. Bí ó bá fẹ́ aya mìíràn fún ara rẹ̀, kò gbọdọ̀ dín oúnjẹ ẹrubinrin yìí kù, tabi aṣọ rẹ̀ tabi àwọn ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aya. Bí olówó ẹrubinrin yìí bá kọ̀, tí kò ṣe àwọn nǹkan mẹtẹẹta náà fún ẹrubinrin rẹ̀, ẹrubinrin náà lẹ́tọ̀ọ́ láti jáde ní ilé rẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́ láìsan ohunkohun. “Bí ẹnikẹ́ni bá lu eniyan pa, pípa ni a óo pa òun náà. Ṣugbọn bí olúwarẹ̀ kò bá mọ̀ọ́nmọ̀ pa á, tí ó jẹ́ pé ó ṣèèṣì ni, irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè sálọ sí ibìkan tí n óo yàn fún yín. Ṣugbọn bí ẹnìkan bá mọ̀ọ́nmọ̀ bá ẹlòmíràn jà, tí ó sì fi ọgbọ́n àrékérekè pa á, bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá sálọ sí ibi pẹpẹ mi, fífà ni kí ẹ fà á kúrò níbi pẹpẹ náà kí ẹ sì pa á. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá lu baba tabi ìyá rẹ̀, pípa ni kí wọ́n pa òun náà. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jí eniyan gbé, kì báà jẹ́ pé ó ti tà á, tabi kí wọ́n ká a mọ́ ọn lọ́wọ́, pípa ni kí wọ́n pa á. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé baba tabi ìyá rẹ̀ ṣépè, pípa ni kí wọ́n pa á. “Bí eniyan meji bá ń jà, tí ọ̀kan bá fi òkúta tabi ẹ̀ṣẹ́ lu ekeji, tí ẹni tí wọ́n lù náà kò bá kú, ṣugbọn tí ó farapa, bí ẹni tí wọ́n lù tí ó farapa náà bá dìde, tí ó sì ń fi ọ̀pá rìn kiri, ẹni tí ó lù ú bọ́ lọ́wọ́ ikú, ṣugbọn dandan ni kí ó san owó fún àkókò tí ẹni tí ó lù náà lò ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn, kí ó sì ṣe ètò ìtọ́jú rẹ̀ títí yóo fi sàn. “Bí ẹnìkan bá lu ẹrukunrin tabi ẹrubinrin rẹ̀ ní kùmọ̀, tí ẹrú náà bá kú mọ́ ọn lọ́wọ́, olúwarẹ̀ yóo jìyà. Ṣugbọn bí ẹrú náà bá gbé odidi ọjọ́ kan tabi meji kí ó tó kú, kí ẹnikẹ́ni má jẹ olówó ẹrú náà níyà, nítorí òun ni ó ni owó tí ó fi rà á. “Bí àwọn eniyan bá ń jà, tí wọ́n sì ṣe aboyún léṣe, tóbẹ́ẹ̀ tí oyún rẹ̀ bàjẹ́ mọ́ ọn lára, ṣugbọn tí òun gan-an kò kú, ẹni tí ó ṣe aboyún náà léṣe níláti san iyekíye tí ọkọ rẹ̀ bá sọ pé òun yóo gbà bí owó ìtanràn, tí onídàájọ́ bá ti fi ọwọ́ sí i. Ṣugbọn bí aboyún náà bá kú tabi bí ó bá farapa, kí wọ́n pa ẹni tí ó ṣe é léṣe náà. Bí ẹnìkan bá fọ́ eniyan lójú, kí wọ́n fọ́ ojú tirẹ̀ náà; bí ẹnìkan bá ká eniyan léyín, kí wọ́n ká eyín tirẹ̀ náà, bí ẹnìkan bá gé eniyan lọ́wọ́, kí wọ́n gé ọwọ́ tirẹ̀ náà, bí ẹnìkan bá gé eniyan lẹ́sẹ̀, kí wọ́n gé ẹsẹ̀ tirẹ̀ náà. Bí ẹnìkan bá fi iná jó eniyan, kí wọ́n fi iná jó òun náà, bí ẹnìkan bá ṣá eniyan lọ́gbẹ́, kí wọ́n ṣá òun náà lọ́gbẹ́, bí ẹnìkan bá na eniyan lẹ́gba, kí wọ́n na òun náà lẹ́gba. “Bí ẹnìkan bá gbá ẹrukunrin tabi ẹrubinrin rẹ̀ lójú, tí ojú náà sì fọ́, olúwarẹ̀ yóo dá ẹrú náà sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́ láìgba ohunkohun lọ́wọ́ rẹ̀, nítorí pé ó ti fọ́ ọ lójú. Bí ó bá yọ eyín ẹrukunrin tabi ẹrubinrin rẹ̀, yóo dá ẹrú náà sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́, nítorí pé ó ti yọ ọ́ léyín. “Bí mààlúù bá kan eniyan pa, kí wọ́n sọ mààlúù náà ní òkúta pa. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ ẹran rẹ̀; ṣugbọn kí ẹnikẹ́ni má ṣe jẹ ẹni tí ó ni mààlúù náà níyà. Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ mààlúù náà ti kan eniyan tẹ́lẹ̀, tí wọ́n sì ti kìlọ̀ fún ẹni tí ó ni ín, tí kò sì so ó mọ́lẹ̀, bí ó bá pa eniyan, kí wọn sọ mààlúù náà ní òkúta pa, kí wọn sì pa ẹni tí ó ni ín pẹlu. Ṣugbọn bí wọ́n bá gbà pé kí ẹni tí ó ni ín san owó ìtanràn, ó níláti san iyekíye tí wọ́n bá sọ pé kí ó san, kí ó baà lè ra ẹ̀mí ara rẹ̀ pada. Bí irú mààlúù tí ó ti kan eniyan pa tẹ́lẹ̀ rí yìí bá tún kan ọmọ ẹnìkan pa, kì báà ṣe ọkunrin tabi obinrin, irú ẹ̀tọ́ kan náà tí a sọ yìí ni wọ́n gbọdọ̀ ṣe fún ẹni tí ó ni mààlúù náà. Bí mààlúù náà bá kan ẹrú ẹnìkan pa, kì báà ṣe ẹrukunrin tabi ẹrubinrin, ẹni tí ó ni mààlúù náà níláti san ọgbọ̀n ṣekeli fadaka fún ẹni tí ó ni ẹrú tí mààlúù pa, kí wọ́n sì sọ mààlúù náà ní òkúta pa. “Bí ẹnìkan bá gbẹ́ kòtò sílẹ̀, tí kò bá bò ó, tabi tí ó gbẹ́ kòtò tí kò sì dí i, bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tabi mààlúù bá já sinu kòtò yìí, tí ó sì kú, ẹni tí ó gbẹ́ kòtò yìí gbọdọ̀ san owó mààlúù tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà fún ẹni tí ó ni ín, òkú ẹran yìí yóo sì di ti ẹni tí ó gbẹ́ kòtò. Bí mààlúù ẹnìkan bá pa ti ẹlòmíràn, àwọn mejeeji yóo ta mààlúù tí ó jẹ́ ààyè, wọn yóo pín owó rẹ̀, wọn yóo sì pín òkú mààlúù náà pẹlu. Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé mààlúù yìí ti máa ń kàn tẹ́lẹ̀, tí ẹni tí ó ni ín kò sì mú un so, yóo fi mààlúù mìíràn rọ́pò èyí tí mààlúù rẹ̀ pa, òkú mààlúù yóo sì di tirẹ̀. “Bí ẹnìkan bá jí akọ mààlúù kan tabi aguntan kan gbé, tí ó bá pa á, tabi tí ó tà á, yóo san akọ mààlúù marun-un dípò ẹyọ kan ati aguntan mẹrin dípò aguntan kan. Tí kò bá ní ohun tí yóo fi tán ọ̀ràn náà, wọn yóo ta òun fúnra rẹ̀ láti san ohun tí ó jí. Bí a bá ká olè mọ́ ibi tí ó ti ń fọ́lé lóru, tí a sì lù ú pa, ẹni tí ó lù ú pa kò jẹ̀bi. Ṣugbọn tí ó bá jẹ́ pé lojumọmọ ni, ẹ̀bi wà fún ẹni tí ó lù ú pa. Ṣugbọn tí ọwọ́ bá tẹ olè lojumọmọ, ó níláti san ohun tí ó jí pada. Bí wọ́n bá ká ẹran ọ̀sìn tí olè jí gbé mọ́ ọn lọ́wọ́ láàyè, kì báà ṣe akọ mààlúù, tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, tabi aguntan; ìlọ́po meji ni yóo fi san pada. “Bí ẹnìkan bá jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn rẹ̀ jẹ oko olóko, tabi ọgbà àjàrà ẹlòmíràn, tabi tí ó bá da ẹran wọ inú oko olóko tí wọ́n sì jẹ nǹkan ọ̀gbìn inú rẹ̀, ibi tí ó dára jùlọ ninu oko tabi ọgbà àjàrà tirẹ̀ ni yóo fi dí i fún ẹni tí ó ni oko tabi ọgbà àjàrà tí ẹran rẹ̀ jẹ. “Bí ẹnìkan bá dáná, tí iná náà bá ràn mọ́ koríko, tí ó bá jó oko olóko, tí ó sì jó ọkà tí wọ́n ti kórè jọ tabi tí ó wà lóòró, olúwarẹ̀ gbọdọ̀ san òmíràn pada fún olóko. “Bí ẹnìkan bá fi owó tabi ìṣúra kan pamọ́ sí ọwọ́ aládùúgbò rẹ̀, tí olè bá gbé e lọ mọ́ aládùúgbò rẹ̀ yìí lọ́wọ́, bí ọwọ́ bá tẹ olè yìí, ìlọ́po meji ohun tí ó gbé ni yóo fi san. Bí ọwọ́ kò bá wá tẹ olè, ẹni tí ó gba ìṣúra pamọ́ yìí gbọdọ̀ wá sí ilé Ọlọrun kí ó fi Ọlọrun ṣẹ̀rí pé òun kò fi ọwọ́ kan ìṣúra tí aládùúgbò òun fi pamọ́ sí òun lọ́wọ́. “Nígbàkúùgbà tí ohun ìní bá di àríyànjiyàn láàrin eniyan meji, kì báà jẹ́ mààlúù, tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, tabi aguntan, tabi aṣọ, tabi ohunkohun tí ó bá ti sọnù, tí ó sì di àríyànjiyàn, àwọn mejeeji tí wọn ń lọ́ nǹkan mọ́ ara wọn lọ́wọ́ gbọdọ̀ wá sí ilé Ọlọrun, kí wọ́n sì fi Ọlọrun ṣẹ̀rí, ẹni tí Ọlọrun bá dá lẹ́bi yóo san ìlọ́po meji nǹkan náà fún ẹnìkejì rẹ̀. “Bí ẹnìkan bá fún aládùúgbò rẹ̀ ní ẹran sìn, kì báà ṣe kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tabi mààlúù, tabi aguntan, bí ẹran náà bá kú tabi kí ó farapa, tabi tí ó bá rìn lọ tí kò sì sí ẹni tí ó rí i, aládùúgbò náà yóo lọ sí ilé Ọlọrun, yóo sì fi OLUWA ṣẹ̀rí pé òun kọ́ ni òun jí ẹran tí wọn fún òun sìn. Ẹni tí ó fún un ní ẹran sìn yóo faramọ́ ìbúra yìí, kò sì ní gbẹ̀san mọ́. Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé wọ́n jí i gbé mọ́ ọn lọ́wọ́ ni, yóo san ẹ̀san fún ẹni tí ó ni ín. Bí ó bá jẹ́ pé ẹranko burúkú ni ó pa á, bí ó bá ní ohun tí ó lè fi ṣe ẹ̀rí, tí ó sì fi ohun náà han ẹni tí ó ni ẹran náà, kò ní san ẹ̀san ẹran náà pada. “Bí ẹnìkan bá yá ẹran ọ̀sìn kẹ́ran ọ̀sìn lọ́wọ́ aládùúgbò rẹ̀, tí ẹran náà bá farapa tabi tí ó kú, tí kò sì sí olówó ẹran náà níbẹ̀, ẹni tí ó yá ẹran náà níláti san án pada. Ṣugbọn bí ẹni tí ó ni ẹran náà bá wà níbẹ̀ nígbà tí ó kú, ẹni tí ó yá a kò ní san ẹ̀san pada. Bí ó bá jẹ́ pé owó ni wọ́n fi yá ẹran náà lọ tí ó fi kú, a jẹ́ pé orí iṣẹ́ owó rẹ̀ ni ó kú sí. “Bí ẹnìkan bá tan wundia tí kì í ṣe àfẹ́sọ́nà ẹnikẹ́ni, tí ó sì bá wundia náà lòpọ̀, ó gbọdọ̀ san owó orí rẹ̀ kí ó sì gbé e níyàwó. Bí baba wundia náà bá kọ̀ jálẹ̀ pé òun kò ní fi ọmọ òun fún un, yóo san iye owó tí wọ́n bá ń san ní owó orí wundia tí kò mọ ọkunrin. “Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí àjẹ́ wà láàyè. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹranko lòpọ̀, pípa ni kí wọ́n pa á. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá rúbọ sí oriṣa-koriṣa kan lẹ́yìn OLUWA, píparun ni kí wọ́n pa á run. “Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ pọ́n àlejò lójú tabi kí ó ni ín lára, nítorí pé ẹ̀yin náà ti jẹ́ àlejò rí ní ilẹ̀ Ijipti. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ fìyà jẹ opó tabi aláìníbaba. Bí ẹnikẹ́ni bá fìyà jẹ wọ́n, tí wọ́n bá ké pè mí, dájúdájú n óo gbọ́ igbe wọn; ibinu mi yóo sì ru sí yín, n óo fi idà pa yín, àwọn aya yín yóo di opó, àwọn ọmọ yín yóo sì di aláìníbaba. “Bí o bá yá ẹnikẹ́ni lówó ninu àwọn eniyan mi, tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ, tí ó ṣe aláìní, má ṣe bí àwọn tí wọn ń fi owó wọn gba èlé, má gba èlé lórí owó tí o yá a. Bí aládùúgbò rẹ bá fi ẹ̀wù rẹ̀ dógò lọ́dọ̀ rẹ, tí o sì gbà á, dá a pada fún un kí oòrùn tó wọ̀; nítorí pé ẹ̀wù yìí ni àwọ̀lékè kan ṣoṣo tí ó ní, òun kan náà sì ni aṣọ ìbora rẹ̀. Àbí aṣọ wo ni ó tún ní tí yóo fi bora sùn? Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ó bá ké pè mí, n óo dá a lóhùn, nítorí pé aláàánú ni mí. “O kò gbọdọ̀ kẹ́gàn Ọlọrun, o kò sì gbọdọ̀ gbé ìjòyè àwọn eniyan rẹ ṣépè. “O kò gbọdọ̀ jáfara láti mú ninu ọpọlọpọ ọkà rẹ ati ọpọlọpọ ọtí waini rẹ láti fi rúbọ sí mi. “O níláti fún mi ní àkọ́bí rẹ ọkunrin pẹlu. Bákan náà ni àkọ́bí mààlúù rẹ ati ti aguntan rẹ, tí wọ́n bá jẹ́ akọ. Fi wọ́n sílẹ̀ pẹlu ìyá wọn fún ọjọ́ meje, ní ọjọ́ kẹjọ o níláti fi wọ́n rúbọ sí mi. “Ẹ gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí a yà sọ́tọ̀ fún mi, nítorí náà, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ òkú ẹran tí ẹranko bá pa ninu ìgbẹ́, ajá ni kí ẹ gbé irú ẹran bẹ́ẹ̀ fún. “O kò gbọdọ̀ lọ́wọ́ sí àhesọ tí kò ní òtítọ́ ninu. O kò gbọdọ̀ bá eniyan burúkú pa ìmọ̀ pọ̀ láti jẹ́rìí èké. O kò gbọdọ̀ bá ọ̀pọ̀ eniyan kẹ́gbẹ́ láti ṣe ibi, tabi kí o tẹ̀lé ọ̀pọ̀ eniyan láti jẹ́rìí èké tí ó lè yí ìdájọ́ po. O kò gbọdọ̀ ṣe ojuṣaaju sí talaka lórí ẹjọ́ rẹ̀. “Bí o bá pàdé akọ mààlúù ọ̀tá rẹ tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ tí ń ṣìnà lọ, o níláti fà á pada wá fún un. Bí o bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹni tí ó kórìíra rẹ, tí ẹrù wó kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà mọ́lẹ̀, tí kò lè lọ mọ́, o kò gbọdọ̀ gbójú kúrò kí o fi sílẹ̀ níbẹ̀, o níláti bá a sọ ẹrù náà kalẹ̀. “O kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ òdodo tí ó tọ́ sí talaka po nígbà tí ó bá ní ẹjọ́. O kò gbọdọ̀ fi ẹ̀sùn èké kan ẹnikẹ́ni, o kò sì gbọdọ̀ pa aláìṣẹ̀ tabi olódodo nítorí pé, èmi, OLUWA kò ní dá eniyan burúkú láre. O kò gbọdọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ a máa fọ́ àwọn aláṣẹ lójú, kì í jẹ́ kí wọn rí ẹ̀tọ́, a sì máa mú kí wọn sọ ẹjọ́ aláre di ẹ̀bi. “O kò gbọdọ̀ pọ́n àlejò lójú, ẹ mọ̀ bí ọkàn àlejò ti rí, nítorí ẹ̀yin pàápàá jẹ́ àlejò rí ní ilẹ̀ Ijipti. “Ọdún mẹfa ni kí o fi máa fúnrúgbìn sórí ilẹ̀ rẹ kí o sì fi máa kórè àwọn ohun ọ̀gbìn inú rẹ̀. Ṣugbọn ní ọdún keje, o gbọdọ̀ fi oko náà sílẹ̀ kí ó sinmi, kí àwọn talaka ninu yín náà lè rí oúnjẹ jẹ, kí àwọn ẹranko sì jẹ ninu èyí tí àwọn talaka bá jẹ kù. Bẹ́ẹ̀ ni o gbọdọ̀ ṣe ọgbà àjàrà rẹ, ati ọgbà olifi rẹ pẹlu. “Ọjọ́ mẹfa ni kí o fi ṣe iṣẹ́, ṣugbọn ní ọjọ́ keje, kí o sinmi; àtìwọ ati akọ mààlúù rẹ, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ; kí ara lè tu ọmọ iranṣẹbinrin rẹ ati àlejò rẹ. “Máa ṣe akiyesi gbogbo ohun tí mo ti sọ fún ọ, má sì ṣe bọ oriṣa kankan, má tilẹ̀ jẹ́ kí n gbọ́ orúkọ wọn lẹ́nu rẹ. “Ìgbà mẹta ni o níláti máa ṣe àjọ̀dún fún mi ní ọdọọdún. O níláti máa ṣe àjọ̀dún àìwúkàrà; gẹ́gẹ́ bí mo ti pa á láṣẹ fún ọ; ọjọ́ meje ni o gbọdọ̀ fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, ní àkókò tí mo yà sọ́tọ̀ ninu oṣù Abibu, nítorí pé ninu oṣù náà ni o jáde ní ilẹ̀ Ijipti. Ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ wá sí iwájú mi ní ọwọ́ òfo. “O gbọdọ̀ ṣe àjọ̀dún ìkórè nígbà tí o bá kórè àkọ́so àwọn ohun tí o gbìn sinu oko rẹ. “Ní òpin ọdún, nígbà tí o bá parí ìkórè gbogbo èso oko rẹ, o gbọdọ̀ ṣe àjọ̀dún ìkórè. Ẹẹmẹta ní ọdọọdún ni gbogbo ọkunrin yín níláti wá siwaju èmi OLUWA Ọlọrun yín. “Nígbà tí o bá fi ohun ẹlẹ́mìí rúbọ sí mi, burẹdi tí o bá fi rúbọ pẹlu rẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́ èyí tí kò ní ìwúkàrà ninu, ọ̀rá ẹran tí o bá fi rúbọ sí mi kò sì gbọdọ̀ kù di ọjọ́ keji. “Ohunkohun tí o bá kọ́ kórè ninu oko rẹ, ilé OLUWA Ọlọrun rẹ ni o gbọdọ̀ mú un wá. “O kò gbọdọ̀ bọ ọmọ ẹran ninu omi wàrà ìyá rẹ̀. “Wò ó, mo rán angẹli kan ṣiwaju rẹ láti pa ọ́ mọ́ ní ọ̀nà rẹ, ati láti mú ọ wá sí ibi tí mo ti tọ́jú fún ọ. Máa fetí sí ohun tí angẹli náà bá sọ fún ọ, kí o sì gbọ́ràn sí i lẹ́nu, má ṣe fi agídí ṣe ìfẹ́ inú rẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí pé èmi ni mo rán an, kò sì ní dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́. Ṣugbọn bí o bá gbọ́ tirẹ̀, tí o sì ṣe bí mo ti wí, nígbà náà ni n óo gbógun ti àwọn tí ó bá gbógun tì ọ́, n óo sì dojú ìjà kọ àwọn ọ̀tá rẹ. Nígbà tí angẹli mi bá ń lọ níwájú rẹ, tí ó bá mú ọ dé ilẹ̀ àwọn ará Amori, ati ti àwọn ará Hiti, ati ti àwọn ará Perisi, ati ti àwọn ará Kenaani, ati ti àwọn ará Hifi, ati ti àwọn ará Jebusi, tí mo bá sì pa wọ́n run, o kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún àwọn oriṣa wọn, o kò sì gbọdọ̀ bọ wọ́n, tabi kí o hu irú ìwà ìbọ̀rìṣà tí àwọn ará ibẹ̀ ń hù. Wíwó ni kí o wó àwọn ilé oriṣa wọn lulẹ̀, kí o sì fọ́ gbogbo àwọn òpó wọn túútúú. Èmi OLUWA Ọlọrun yín ni kí ẹ máa sìn. N óo pèsè ọpọlọpọ nǹkan jíjẹ ati nǹkan mímu fún yín, n óo sì mú àìsàn kúrò láàrin yín. Ẹyọ oyún kan kò ní bàjẹ́ lára àwọn obinrin yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹyọ obinrin kan kò ní yàgàn ninu gbogbo ilẹ̀ yín. N óo jẹ́ kí ẹ gbó, kí ẹ sì tọ́. “N óo da jìnnìjìnnì bo gbogbo àwọn tí ẹ̀ ń lọ dojú ìjà kọ, rúdurùdu yóo sì bẹ́ sí ààrin wọn, gbogbo àwọn ọ̀tá yín ni yóo máa sálọ, nígbàkúùgbà tí wọ́n bá gbúròó yín. N óo rán àwọn agbọ́n ńlá ṣáájú yín, tí yóo lé àwọn ará Hifi ati àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Hiti jáde fún yín. N kò ní tíì lé wọn jáde fún ọdún kan, kí ilẹ̀ náà má baà di aṣálẹ̀, kí àwọn ẹranko sì pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn yóo gba gbogbo ilẹ̀ náà mọ́ yín lọ́wọ́. Díẹ̀díẹ̀ ni n óo máa lé wọn jáde fún yín, títí tí ẹ óo fi di pupọ tí ẹ óo sì gba gbogbo ilẹ̀ náà. Ilẹ̀ yín yóo lọ títí kan Òkun Pupa, ati títí lọ kan òkun àwọn ará Filistia, láti aṣálẹ̀ títí lọ kan odò Yufurate, nítorí pé n óo fi àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà le yín lọ́wọ́, ẹ óo sì lé wọn jáde. Ẹ kò gbọdọ̀ bá àwọn tabi àwọn oriṣa wọn dá majẹmu. Wọn kò gbọdọ̀ gbé orí ilẹ̀ yín, kí wọ́n má baà mú yín ṣẹ èmi OLUWA; nítorí pé bí ẹ bá bọ oriṣa wọn, ọrùn ara yín ni ẹ tì bọ tàkúté.” OLUWA wí fún Mose pé, “Ẹ gòkè tọ èmi OLUWA wá, ìwọ ati Aaroni, ati Nadabu, ati Abihu, ati aadọrin ninu àwọn àgbààgbà Israẹli, kí ẹ sì sin èmi OLUWA ní òkèèrè. Ìwọ Mose nìkan ni kí o súnmọ́ mi, kí àwọn yòókù má ṣe súnmọ́ mi, má sì jẹ́ kí àwọn eniyan ba yín gòkè wá rárá.” Mose bá tọ àwọn eniyan náà lọ, ó sọ gbogbo ohun tí OLUWA sọ fún un fún wọn, ati gbogbo ìlànà tí ó là sílẹ̀, gbogbo àwọn eniyan náà sì fi ẹnu kò, wọ́n dáhùn pé, “Gbogbo ohun tí OLUWA wí ni a óo ṣe.” Mose bá kọ gbogbo ọ̀rọ̀ OLUWA sílẹ̀. Nígbà tí ó di òwúrọ̀ kutukutu, ó dìde, ó tẹ́ pẹpẹ kan sí ìsàlẹ̀ òkè náà, ó ri ọ̀wọ̀n mejila mọ́lẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún ẹ̀yà Israẹli kọ̀ọ̀kan. Ó sì rán àwọn kan ninu àwọn ọdọmọkunrin Israẹli, pé kí wọ́n lọ fi mààlúù rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia sí OLUWA. Mose gba ìdajì ninu ẹ̀jẹ̀ ẹran náà sinu àwo ńlá, ó sì da ìdajì yòókù sí ara pẹpẹ náà. Ó mú ìwé majẹmu náà, ó kà á sí etígbọ̀ọ́ gbogbo àwọn eniyan, wọ́n sì dáhùn pé, “Gbogbo ohun tí OLUWA wí ni a óo ṣe, a óo sì gbọ́ràn.” Ni Mose bá gba ẹ̀jẹ̀ ẹran yòókù tí ó wà ninu àwo, ó wọ́n ọn sí àwọn eniyan náà lára, ó ní, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ majẹmu tí OLUWA bá yín dá, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí mo sọ.” Mose ati Aaroni, ati Nadabu, ati Abihu, ati aadọrin ninu àwọn àgbààgbà Israẹli bá gòkè lọ, wọ́n sì rí Ọlọrun Israẹli. Wọ́n rí kinní kan ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ tí ó dàbí pèpéle tí a fi òkúta safire ṣe, ó mọ́lẹ̀ kedere bí ojú ọ̀run. Ọlọrun kò sì pa àwọn àgbààgbà Israẹli náà lára rárá, wọ́n rí Ọlọrun, wọ́n jẹ, wọ́n sì mu. OLUWA wí fún Mose pé, “Gun orí òkè tọ̀ mí wá, kí o dúró sibẹ, n óo sì kó wàláà tí wọ́n fi òkúta ṣe fún ọ, tí mo kọ àwọn òfin ati ìlànà sí, fún ìtọ́ni àwọn eniyan yìí.” Mose bá gbéra, òun ati Joṣua iranṣẹ rẹ̀, ó gun orí òkè Ọlọrun lọ. Ó sọ fún àwọn àgbààgbà pé, “Ẹ dúró níhìn-ín dè wá títí a óo fi pada wá bá yín. Aaroni ati Huri wà pẹlu yín, bí ẹnikẹ́ni bá ní àríyànjiyàn kan, kí ó kó o tọ̀ wọ́n lọ.” Mose bá gun orí òkè náà lọ, ìkùukùu sì bo orí òkè náà. Ògo OLUWA sọ̀kalẹ̀ sórí òkè Sinai, ìkùukùu sì bò ó fún ọjọ́ mẹfa, ní ọjọ́ keje, OLUWA pe Mose láti inú ìkùukùu náà. Lójú àwọn eniyan Israẹli, ìrísí ògo OLUWA lórí òkè náà dàbí iná ńlá tí ń jóni ní àjórun. Mose wọ inú ìkùukùu náà lọ, ó gun orí òkè náà, ó sì wà níbẹ̀ fún ogoji ọjọ́, tọ̀sán-tòru. OLUWA rán Mose ó ní, “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n gba ọrẹ jọ fún mi, ọwọ́ ẹnikẹ́ni tí ó bá ti ọkàn rẹ̀ wá láti ṣe ọrẹ àtinúwá ni kí wọ́n ti gba ọrẹ náà. Àwọn nǹkan ọrẹ tí wọn yóo gbà lọ́wọ́ wọn ni: wúrà, fadaka, idẹ; aṣọ aláró, aṣọ elése àlùkò, aṣọ pupa, aṣọ funfun, ati irun ewúrẹ́; awọ àgbò tí wọ́n ṣe, tí ó jẹ́ pupa, ati ti ewúrẹ́, igi akasia; òróró fún àwọn fìtílà, ati àwọn èròjà olóòórùn dídùn fún òróró tí wọn ń ta sí eniyan lórí, ati turari, òkúta onikisi ati àwọn òkúta tí wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ ọnà sára efodu tí àwọn alufaa ń wọ̀, ati ohun tí wọn ń dà bo àyà; kí wọ́n sì ṣe ibùgbé fún mi, kí n lè máa gbé ààrin wọn. Bí mo ti júwe fún ọ gan-an ni kí o ṣe àgọ́ náà ati gbogbo àwọn ohun èlò inú rẹ̀. “Kí wọ́n fi igi akasia kan àpótí kan, kí ó gùn ní ìwọ̀n igbọnwọ meji ààbọ̀, kí ó fẹ̀ ní igbọnwọ kan ààbọ̀, kí ó sì ga ní igbọnwọ kan ààbọ̀. Fi ojúlówó wúrà bò ó ninu ati lóde, kí o sì fi wúrà gbá a létí yípo. Fi wúrà ṣe òrùka mẹrin, kí o jó wọn mọ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹrẹẹrin; meji lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni, meji lẹ́gbẹ̀ẹ́ keji. Fi igi akasia ṣe àwọn ọ̀pá, kí o sì fi wúrà bò wọ́n. Kí o ti àwọn ọ̀pá náà bọ àwọn òrùka tí wọ́n wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji àpótí náà láti máa fi gbé e. Kí àwọn ọ̀pá yìí máa wà ninu àwọn òrùka tí ó wá lẹ́gbẹ̀ẹ́ àpótí yìí nígbà gbogbo, kí ẹnikẹ́ni má ṣe fà wọ́n yọ. Kí o fi àkọsílẹ̀ majẹmu ẹ̀rí tí n óo gbé lé ọ lọ́wọ́ sinu àpótí náà. “Lẹ́yìn náà, fi ojúlówó wúrà ṣe ìtẹ́ àánú; kí ó gùn ní ìwọ̀n igbọnwọ meji ààbọ̀, kí ó sì fẹ̀ ní ìwọ̀n igbọnwọ kan ààbọ̀. Fi wúrà tí wọ́n fi ọmọ owú lù ṣe Kerubu meji, kí ọ̀kọ̀ọ̀kan wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji ìtẹ́ àánú náà. Àṣepọ̀ mọ́ ìtẹ́ àánú ni kí o ṣe àwọn Kerubu náà, kí ọ̀kan wà ní ìsàlẹ̀, kí ekeji sì wà ní òkè rẹ̀. Kí àwọn Kerubu náà na ìyẹ́ wọn bo ìtẹ́ àánú, kí wọ́n kọjú sí ara wọn, kí àwọn mejeeji sì máa wo ìtẹ́ àánú náà. Gbé ìtẹ́ àánú náà ka orí àpótí náà, kí o sì fi ẹ̀rí majẹmu tí n óo fún ọ sinu rẹ̀. Níbẹ̀ ni n óo ti máa pàdé rẹ; láti òkè ìtẹ́ àánú, ní ààrin àwọn Kerubu mejeeji tí wọ́n wà lórí àpótí ẹ̀rí ni n óo ti máa bá ọ sọ nípa gbogbo òfin tí mo bá fẹ́ fún àwọn eniyan Israẹli. “Fi igi akasia kan tabili kan, kí ó gùn ní ìwọ̀n igbọnwọ meji, kí ó fẹ̀ ní ìwọ̀n igbọnwọ kan, kí ó sì ga ní ìwọ̀n igbọnwọ kan ààbọ̀. Yọ́ ojúlówó wúrà bò ó, kí o sì yọ́ ojúlówó wúrà sí gbogbo etí rẹ̀ yípo. Lẹ́yìn náà, ṣe ìgbátí kan yíká etí tabili náà, kí ó fẹ̀ ní ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan, kí o sì yọ́ wúrà bo ìgbátí náà yípo. Lẹ́yìn náà, ṣe òrùka wúrà mẹrin, kí o sì jó òrùka kọ̀ọ̀kan mọ́ ibi ẹsẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Kí òrùka kọ̀ọ̀kan súnmọ́ ìgbátí tabili náà, òrùka wọnyi ni wọn yóo máa ti ọ̀pá bọ̀ láti fi gbé tabili náà. Fi igi akasia ṣe ọ̀pá, kí o sì yọ́ wúrà bò wọ́n; àwọn ọ̀pá wọnyi ni wọn yóo máa fi gbé tabili náà. Fi ojúlówó wúrà ṣe àwọn àwo ati àwo kòtò fún turari ati ìgò ati abọ́ tí wọn yóo fi máa ta ohun mímu sílẹ̀ fún ètùtù. Gbé tabili náà kalẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí, kí burẹdi ìfihàn sì máa wà ní orí rẹ̀ nígbà gbogbo. “Fi ojúlówó wúrà ṣe ọ̀pá fìtílà kan. Wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni kí wọ́n fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ ati ọ̀pá fìtílà náà; kí wọ́n ṣe é ní àṣepọ̀ mọ́ òkè ọ̀pá fìtílà náà; kí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà bí òdòdó tí wọn yóo fi dárà sí ìdí fìtílà kọ̀ọ̀kan. Ṣe ẹ̀ka mẹfa sára ọ̀pá fìtílà náà, mẹta ní ẹ̀gbẹ́ kinni, ati mẹta ní ẹ̀gbẹ́ keji. Kí ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀ka mẹfẹẹfa yìí ní iṣẹ́ ọnà bí òdòdó aláràbarà mẹta mẹta tí ó dàbí òdòdó alimọndi. Kí òdòdó aláràbarà mẹrin wà lórí ọ̀pá fìtílà náà gan-an, kí àwọn òdòdó náà dàbí alimọndi tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ so, kí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ èso kéékèèké kọ̀ọ̀kan wà lábẹ́ ẹ̀ka meji meji tí ó ya lára ọ̀pá fìtílà náà. Àṣepọ̀ ni kí wọ́n ṣe ọ̀pá fìtílà, ati àwọn ẹ̀ka rẹ̀, ati àṣẹ̀ṣẹ̀yọ èso kékeré abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀. Ojúlówó wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni kí wọ́n sì fi ṣe gbogbo rẹ̀. Ṣe fìtílà meje fún ọ̀pá fìtílà náà, kí o sì gbé wọn ka orí ọ̀pá náà ní ọ̀nà tí gbogbo wọn yóo fi kọjú siwaju. Ojúlówó wúrà ni kí o fi ṣe ẹnu rẹ̀ ati àwo pẹrẹsẹ rẹ̀, talẹnti wúrà kan ni kí o fi ṣe ọ̀pá fìtílà náà ati gbogbo ohun èlò rẹ̀. Rí i dájú pé o ṣe gbogbo rẹ̀ pátá bí mo ti fi hàn ọ́ ní orí òkè. “Aṣọ títa mẹ́wàá ni kí o fi ṣe inú àgọ́ mi, kí aṣọ náà jẹ́ aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun, kí wọ́n dárà sí aṣọ náà pẹlu àwọ̀ aró, ati àwọ̀ elése àlùkò ati àwọ̀ pupa, kí àwọn tí wọ́n bá mọ iṣẹ́ ọnà ya àwòrán Kerubu sí ara gbogbo aṣọ títa náà. Kí gígùn aṣọ títa kọ̀ọ̀kan jẹ́ igbọnwọ mejidinlọgbọn, kí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹrin, kí àwọn aṣọ títa náà gùn bákan náà, kí wọ́n sì fẹ̀ bákan náà. Rán marun-un ninu àwọn aṣọ títa náà pọ̀, lẹ́yìn náà, rán marun-un yòókù pọ̀. Fi aṣọ aláwọ̀ aró ṣe ojóbó sí etí ẹ̀gbẹ́ tí ó wà ní òde ninu aṣọ àránpọ̀ kọ̀ọ̀kan. Aadọta ojóbó ni kí o ṣe sí àránpọ̀ aṣọ kinni, lẹ́yìn náà ṣe aadọta ojóbó sí àránpọ̀ aṣọ keji, kí àwọn ojóbó náà lè kọ ojú sí ara wọn. Lẹ́yìn náà, ṣe aadọta ìkọ́ wúrà, kí o fi kọ́ àwọn ojóbó àránpọ̀ aṣọ mejeeji, kí àgọ́ náà lè dúró ní odidi kan ṣoṣo. “Fi awẹ́ aṣọ mọkanla tí wọ́n fi irun ewúrẹ́ ṣe, ṣe ìbòrí kan fún àgọ́ náà. Kí gígùn ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu aṣọ náà jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ, kí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹrin, kí àwọn aṣọ mọkọọkanla gùn bákan náà, kí wọ́n sì fẹ̀ bákan náà. Rán marun-un ninu àwọn aṣọ náà pọ̀, lẹ́yìn náà, rán mẹfa yòókù pọ̀, kí o ṣẹ́ aṣọ kẹfa po bo iwájú àgọ́ náà. Ṣe aadọta ojóbó sí awẹ́ tí ó parí àránpọ̀ aṣọ kinni, kí o sì ṣe aadọta ojóbó sí etí awẹ́ tí ó parí aṣọ àránpọ̀ keji. Fi idẹ ṣe aadọta ìkọ́, kí o sì fi wọ́n kọ́ àwọn ojóbó náà, láti mú àwọn àránpọ̀ aṣọ mejeeji náà papọ̀ kí wọ́n lè jẹ́ ìbòrí kan. Jẹ́ kí ìdajì awẹ́ tí ó kù ṣẹ́ bo ẹ̀yìn àgọ́ náà. Jẹ́ kí igbọnwọ kọ̀ọ̀kan tí ó kù ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji àránpọ̀ aṣọ náà ṣẹ́ bo ẹ̀gbẹ́ kinni keji àgọ́ náà. “Lẹ́yìn náà, fi awọ àgbò tí a ṣe ní pupa, ati awọ ewúrẹ́ tí a ṣe dáradára, ṣe ìbòrí keji fún àgọ́ náà. “Igi akasia ni kí o fi ṣe àwọn òpó àgọ́ náà, kí àwọn igi tí yóo dúró ní òòró gùn ní igbọnwọ mẹ́wàá, kí àwọn tí o óo fi dábùú rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kọ̀ọ̀kan ààbọ̀. Kí igi kọ̀ọ̀kan ní àtẹ̀bọ̀ meji, tí wọ́n tẹ̀ bọ inú ara wọn, bẹ́ẹ̀ ni kí o ṣe gbogbo àwọn igi tí wọ́n wà ninu àgọ́ náà. Ogún àkànpọ̀ igi ni kí o ṣe sí ìhà gúsù àgọ́ náà. Ogoji ìtẹ́lẹ̀ fadaka ni kí o ṣe sí àwọn ogún àkànpọ̀ igi náà, ìtẹ́lẹ̀ meji meji sí àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan, kí ìtẹ́lẹ̀ meji wà fún àtẹ̀bọ̀ igi meji ninu olukuluku àkànpọ̀ igi náà. Ṣe ogún àkànpọ̀ igi sí ẹ̀gbẹ́ àríwá àgọ́ náà, ati ogoji ìtẹ́lẹ̀ fadaka, meji meji sí àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan. Àkànpọ̀ igi mẹfa ni kí ó wà lẹ́yìn àgọ́ náà ní apá ìwọ̀ oòrùn. Kí o sì ṣe àkànpọ̀ igi meji meji fún igun mejeeji ẹ̀yìn àgọ́ náà. Jẹ́ kí àwọn àkànpọ̀ igi mejeeji tí wọ́n wà ní igun àgọ́ wà ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìsàlẹ̀, ṣugbọn kí o so wọ́n pọ̀ ní òkè ní ibi ìtẹ̀bọ̀ àkọ́kọ́. Bẹ́ẹ̀ ni kí o ṣe àwọn àkànpọ̀ igi mejeeji tí wọ́n wà ní igun mejeeji. Gbogbo àkànpọ̀ igi yóo jẹ́ mẹjọ, ìtẹ́lẹ̀ fadaka wọn yóo sì jẹ́ mẹrindinlogun, meji meji lábẹ́ àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan. “Fi igi akasia ṣe igi ìdábùú mẹẹdogun; marun-un fún àwọn àkànpọ̀ igi tí wọ́n wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni àgọ́ náà, marun-un fún àwọn àkànpọ̀ igi tí wọ́n wà ní ẹ̀gbẹ́ keji, marun-un yòókù fún àwọn àkànpọ̀ igi tí wọ́n wà ní ẹ̀yìn ní apá ìwọ̀ oòrùn. Kí igi ìdábùú tí ó wà ní ààrin gbùngbùn àkànpọ̀ igi náà gùn láti ẹ̀gbẹ́ kinni dé ẹ̀gbẹ́ keji àgọ́ náà. Yọ́ wúrà bo àwọn àkànpọ̀ igi náà, kí wọ́n sì ní àwọn òrùka wúrà kí wọ́n lè máa ti àwọn igi ìdábùú náà bọ̀ ọ́, yọ́ wúrà bo àwọn igi ìdábùú náà pẹlu. Bí mo ti fi hàn ọ́ ní orí òkè, ni kí o ṣe kọ́ àgọ́ náà. “Ṣe aṣọ títa kan, tí ó jẹ́ aláwọ̀ aró, ati elése àlùkò, ati pupa, ati aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun, kí wọ́n ya àwòrán Kerubu sí i lára. Gbé e kọ́ sórí òpó igi akasia mẹrin, tí ó ní ìkọ́ wúrà. Wúrà ni kí o yọ́ bo gbogbo òpó náà, kí wọ́n sì wà lórí ìtẹ́lẹ̀ fadaka mẹrin. Lára àwọn àtẹ̀bọ̀ ni kí o fi àwọn aṣọ títa náà kọ́, kí o sì gbé àpótí ẹ̀rí náà wọ inú ibi tí aṣọ títa náà wà, aṣọ títa yìí ni yóo ya ibi mímọ́ sọ́tọ̀ kúrò lára ibi mímọ́ jùlọ. Fi ìtẹ́ àánú sórí àpótí ẹ̀rí ninu ibi mímọ́ jùlọ. Kí o gbé tabili kalẹ̀ ní ọwọ́ òde aṣọ títa náà, kí ọ̀pá fìtílà wà ní apá ìhà gúsù àgọ́ náà, ní òdìkejì tabili náà, kí o sì gbé tabili náà kalẹ̀ ní apá àríwá. “Fi aṣọ aláwọ̀ aró ati elése àlùkò, ati aṣọ pupa ati aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun, tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí létí ṣe aṣọ títa kan fún ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà. Ṣe òpó igi akasia marun-un fún aṣọ títa sí ẹnu ọ̀nà náà, kí o sì fi wúrà bo àwọn òpó náà; wúrà ni kí o fi ṣe àwọn ìkọ́ wọn pẹlu, kí o sì ṣe ìtẹ́lẹ̀ idẹ marun-un fún wọn. “Igi akasia ni kí o fi ṣe pẹpẹ, kí ó gùn ní ìwọ̀n igbọnwọ marun-un, kí ó sì fẹ̀ ní ìwọ̀n igbọnwọ marun-un; kí òòró ati ìbú pẹpẹ náà rí bákan náà, kí ó sì ga ní ìwọ̀n igbọnwọ mẹta. Yọ ìwo kọ̀ọ̀kan sí igun rẹ̀ mẹrẹẹrin, àṣepọ̀ ni kí o ṣe àwọn ìwo náà mọ́ pẹpẹ, kí o sì yọ́ idẹ bo gbogbo rẹ̀. Fi idẹ ṣe ìkòkò láti máa kó eérú orí pẹpẹ sí, fi idẹ ṣe ọkọ́, àwo kòtò, ọ̀kọ̀ tí wọ́n fi ń gún ẹran ẹbọ ati àwo ìfọnná, idẹ ni kí o fi ṣe gbogbo àwọn ohun èlò pẹpẹ náà. Idẹ ni kí o fi ṣe asẹ́ ààrò rẹ̀, kí o sì ṣe òrùka idẹ mẹrin, ọ̀kọ̀ọ̀kan sí igun mẹrẹẹrin asẹ́ náà. Ti asẹ́ idẹ náà bọ abẹ́ etí pẹpẹ, tí yóo fi jẹ́ pé asẹ́ náà yóo dé agbede meji pẹpẹ náà sísàlẹ̀. Fi igi akasia ṣe ọ̀pá pẹpẹ, kí o sì yọ́ idẹ bo ọ̀pá náà. Kí o ti àwọn ọ̀pá náà bọ àwọn òrùka ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ, tí ọ̀pá yóo fi wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji pẹpẹ náà nígbà tí wọ́n bá fẹ́ gbé e. Fi pákó ṣe pẹpẹ náà, kí o sì jẹ́ kí ó jin kòtò, bí mo ti fi hàn ọ́ ní orí òkè, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí o ṣe é. “Ṣe àgbàlá kan sinu àgọ́ náà. Aṣọ ọ̀gbọ̀ ni kí o fi ṣe aṣọ títa apá gúsù àgbàlá náà, kí gígùn rẹ̀ jẹ́ ọgọrun-un igbọnwọ, àwọn òpó rẹ̀ yóo jẹ́ ogún, ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ yóo sì jẹ́ ogún bákan náà, idẹ ni o óo fi ṣe wọ́n, ṣugbọn fadaka ni kí o fi ṣe àwọn ìkọ́ ati òpó rẹ̀. Bákan náà, aṣọ tí o óo ta sí ẹ̀gbẹ́ àríwá àgbàlá náà yóo gùn ní ọgọrun-un igbọnwọ, àwọn òpó ti ẹ̀gbẹ́ náà yóo jẹ́ ogún bákan náà, pẹlu ogún ìtẹ́lẹ̀ tí a fi idẹ ṣe, ṣugbọn fadaka ni kí o fi ṣe ìkọ́ ati òpó wọn. Aṣọ títa yóo wà ní ẹ̀gbẹ́ ìwọ̀ oòrùn àgbàlá náà, gígùn rẹ̀ yóo jẹ́ aadọta igbọnwọ, yóo ní òpó mẹ́wàá, òpó kọ̀ọ̀kan yóo ní ìtẹ́lẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Fífẹ̀ àgbàlá náà, láti iwájú títí dé ẹ̀gbẹ́ ìlà oòrùn, yóo jẹ́ aadọta igbọnwọ. Aṣọ títa kan yóo wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà, yóo gùn ní igbọnwọ mẹẹdogun, yóo ní òpó mẹta ati ìtẹ́lẹ̀ mẹta. Aṣọ títa kan yóo wà ní ẹ̀gbẹ́ keji ẹnu ọ̀nà náà, òun náà yóo gùn ní igbọnwọ mẹẹdogun, yóo sì ní òpó mẹta ati ìtẹ́lẹ̀ mẹta bákan náà. Ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà yóo ní aṣọ títa kan tí yóo gùn ní ogún igbọnwọ, aṣọ aláwọ̀ aró, èyí tí ó ní àwọ̀ elése àlùkò ati àwọ̀ pupa fòò ati aṣọ ọ̀gbọ̀ ni kí o fi ṣe aṣọ títa náà, kí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí etí rẹ̀, kí ó ní òpó mẹrin ati ìtẹ́lẹ̀ mẹrin. Fadaka ni kí o fi bo gbogbo òpó inú àgọ́ náà, fadaka náà ni kí o sì fi ṣe gbogbo ìkọ́ àwọn òpó náà, àfi àwọn ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ni kí o fi idẹ ṣe. Gígùn àgbàlá náà yóo jẹ́ ọgọrun-un igbọnwọ, ìbú rẹ̀ yóo jẹ́ aadọta igbọnwọ, gíga rẹ̀ yóo sì jẹ́ igbọnwọ marun-un pẹlu aṣọ títa tí a fi aṣọ ọ̀gbọ̀ ṣe ati ìtẹ́lẹ̀ idẹ. Idẹ ni kí o fi ṣe gbogbo àwọn ohun èlò inú àgọ́ náà ati gbogbo èèkàn rẹ̀, ati gbogbo èèkàn àgbàlá náà. “Pàṣẹ fún àwọn eniyan Israẹli pé kí wọn mú ojúlówó òróró olifi wá fún títan iná, kí wọ́n lè gbé fìtílà kan kalẹ̀ tí yóo máa wà ní títàn nígbà gbogbo. Yóo wà ninu àgọ́ àjọ, lọ́wọ́ ìta aṣọ títa tí ó wà níwájú àpótí ẹ̀rí, kí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ máa tọ́jú rẹ̀ níwájú OLUWA láti àṣáálẹ́ títí di òwúrọ̀. Kí àwọn eniyan Israẹli sì máa pa ìlànà náà mọ́ títí lae, láti ìrandíran. “Lẹ́yìn náà, pe Aaroni arakunrin rẹ sọ́dọ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀ wọnyi: Nadabu, Abihu, Eleasari, ati Itamari. Yà wọ́n sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ọmọ Israẹli, kí wọ́n sì jẹ́ alufaa mi. Sì dá ẹ̀wù mímọ́ kan fún Aaroni, arakunrin rẹ, kí ó lè fún un ní iyì ati ọlá. Pe gbogbo àwọn tí wọ́n mọ iṣẹ́ ọnà jọ, àwọn tí mo fi ìmọ̀ ati òye iṣẹ́ ọnà dá lọ́lá, kí wọ́n rán aṣọ alufaa kan fún Aaroni láti yà á sọ́tọ̀ fún mi, gẹ́gẹ́ bí alufaa. Àwọn aṣọ tí wọn yóo rán náà nìwọ̀nyí; ọ̀kan fún ìgbàyà, ati ẹ̀wù efodu, ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ kan, ati ẹ̀wù àwọ̀lékè kan tí a ṣe iṣẹ́ ọnà sí; fìlà kan, ati àmùrè. Wọn yóo rán àwọn aṣọ mímọ́ náà fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ alufaa fún mi. Wọn yóo gba wúrà, aṣọ aláwọ̀ aró, aláwọ̀ elése àlùkò, aláwọ̀ pupa ati aṣọ ọ̀gbọ̀ tí ó ní ìlà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́. “Wọn yóo ṣe efodu wúrà, ati aṣọ aláwọ̀ aró, ati ti aláwọ̀ elése àlùkò, aláwọ̀ pupa ati aṣọ ọ̀gbọ̀ tí ó ní ìlà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́; wọn yóo sì ṣe iṣẹ́ ọnà sí i lára. Kí wọ́n rán àgbékọ́ meji mọ́ etí rẹ̀ mejeeji, tí wọn yóo fi lè máa so ó pọ̀. Irú aṣọ kan náà tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára ni kí wọ́n fi ṣe àmùrè rẹ̀. Iṣẹ́ ọnà kan náà ni kí wọ́n ṣe sí i lára pẹlu wúrà, aṣọ aláwọ̀ aró, aláwọ̀ elése àlùkò, aláwọ̀ pupa, ati aṣọ ọ̀gbọ̀ tí ó ní ìlà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́. Mú òkúta onikisi meji, kí o sì kọ orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli sí ara wọn. Orúkọ ẹ̀yà mẹfa sára òkúta ekinni ati orúkọ ẹ̀yà mẹfa yòókù sára ekeji, kí o to àwọn orúkọ náà bí wọ́n ṣe bí wọn tẹ̀lé ara wọn. Bí oníṣẹ́ ọnà wúrà ti máa ń kọ orúkọ sí ara òrùka èdìdì, ni kí o kọ orúkọ àwọn ọmọ Israẹli sí ara òkúta mejeeji, kí o sì fi wúrà ṣe ìtẹ́lẹ̀ wọn. Lẹ́yìn náà, rán àwọn òkúta mejeeji mọ́ àwọn èjìká efodu náà, gẹ́gẹ́ bí òkúta ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli. Èyí yóo mú kí Aaroni máa mú orúkọ wọn wá siwaju OLUWA fún ìrántí. O óo ṣe àwọn ìtẹ́lẹ̀ wúrà, ati ẹ̀wọ̀n wúrà meji tí a lọ́ pọ̀ bí okùn, kí o sì so àwọn ẹ̀wọ̀n wúrà náà mọ́ àwọn ìtẹ́lẹ̀ wúrà náà. “Ṣe ìgbàyà ìdájọ́, èyí tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà dáradára sí lára, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọnà ara efodu náà: wúrà, aṣọ aláwọ̀ aró, aláwọ̀ elése àlùkò, aláwọ̀ pupa ati aṣọ ọ̀gbọ̀ tí ó ní ìlà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, ni kí o fi ṣe é. Bákan náà ni ìbú ati òòró rẹ̀ yóo rí, ìṣẹ́po meji ni yóo jẹ́, ìbú ati òòró rẹ̀ yóo sì jẹ́ ìká kọ̀ọ̀kan. To òkúta olówó iyebíye sí ara rẹ̀ ní ẹsẹ̀ mẹrin, kí ẹsẹ̀ àkọ́kọ́ jẹ́ òkúta sadiu, ati òkúta topasi, ati òkúta kabọnku. Kí ẹsẹ̀ keji jẹ́ òkúta emeradi, ati òkúta safire, ati òkúta dayamọndi. Kí ẹsẹ̀ kẹta jẹ́ òkúta jasiniti, ati òkúta agate, ati òkúta ametisti. Kí ẹsẹ̀ kẹrin jẹ́ òkúta bẹrili, ati òkúta onikisi, ati òkúta jasiperi, wúrà ni kí wọ́n fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ àwọn òkúta wọnyi. Oríṣìí òkúta mejila ni yóo wà, orúkọ wọn yóo dàbí orúkọ àwọn ọmọ Israẹli; wọn yóo dàbí èdìdì, wọn yóo sì kọ orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli mejila sí ara àwọn òkúta mejeejila, òkúta kan fún ẹ̀yà kan. Fi ojúlówó wúrà ṣe ẹ̀wọ̀n tí a lọ́ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí okùn fún ìgbàyà náà. Kí o da òrùka wúrà meji sí etí kinni keji ìgbàyà náà. Fi ẹ̀wọ̀n wúrà mejeeji bọ inú òrùka mejeeji yìí. So etí kinni keji àwọn ẹ̀wọ̀n mejeeji mọ́ ojú ìdè mejeeji, kí o so ó mọ́ èjìká efodu náà níwájú. Da òrùka wúrà meji, sì dè wọ́n mọ́ etí kinni keji ìgbàyà náà lọ́wọ́ inú, ní ẹ̀gbẹ́ tí ó kan ara efodu. Lẹ́yìn náà, da òrùka wúrà meji mìíràn, kí o dè wọ́n mọ́ ìsàlẹ̀ àwọn èjìká efodu, níwájú ibi tí ó ti so pọ̀ mọ́ àmùrè rẹ̀. Aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́ aláwọ̀ aró ni wọn yóo máa fi bọ inú àwọn òrùka ara efodu ati àwọn òrùka ara ìgbàyà, láti dè wọ́n pọ̀ kí ó lè máa wà lórí àmùrè tí ó wà lára efodu náà, kí ìgbàyà náà má baà tú kúrò lára efodu. “Orúkọ àwọn ọmọ Israẹli yóo máa wà lára Aaroni, lórí ìgbàyà ìdájọ́, ní oókan àyà rẹ̀, nígbà tí ó bá wọ ibi mímọ́ lọ, fún ìrántí nígbà gbogbo níwájú OLUWA. Fi òkúta Urimu ati òkúta Tumimu sí ara ìgbàyà ìdájọ́, kí wọn kí ó sì máa wà ní oókan àyà Aaroni, nígbà tí ó bá lọ siwaju OLUWA. Bẹ́ẹ̀ ni Aaroni yóo ṣe máa ru ìdájọ́ àwọn ọmọ Israẹli sí oókan àyà rẹ̀, nígbà gbogbo níwájú OLUWA. “O óo fi aṣọ aláwọ̀ aró rán ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ sí efodu náà. Yọ ọrùn sí ẹ̀wù náà, kí o sì fi aṣọ bí ọ̀já tẹ́ẹ́rẹ́ gbá a lọ́rùn yípo, bí wọ́n ti máa ń fi aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́ gbá ọrùn ẹ̀wù, kí ó má baà ya. Fi aṣọ aláwọ̀ aró, ati ti elése àlùkò, ati aṣọ pupa ya àwòrán èso pomegiranate sí etí ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ náà nísàlẹ̀, sì fi agogo ojúlówó wúrà kéékèèké kọ̀ọ̀kan la àwọn àwòrán èso pomegiranate náà láàrin, yípo etí àwọ̀kanlẹ̀ efodu náà, nísàlẹ̀. Agogo wúrà kan, àwòrán èso pomegiranate kan, bẹ́ẹ̀ ni kí o tò wọ́n sí etí ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ efodu náà. Èyí ni Aaroni yóo máa wọ̀ nígbà tí ó bá ń ṣe iṣẹ́ alufaa rẹ̀, yóo sì máa gbọ́ ìró rẹ̀ nígbà tí ó bá ń wọ ibi mímọ́ lọ níwájú OLUWA ati ìgbà tí ó bá ń jáde, kí ó má baà kú. “Fi ojúlówó wúrà ṣe ìgbátí kan kí o sì kọ àkọlé sí i gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sí ara òrùka èdìdì, àkọlé náà nìyí: ‘Mímọ́ fún OLUWA.’ Fi aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́, aláwọ̀ aró dè é mọ́ fìlà alufaa níwájú. Nígbà tí Aaroni bá ń rú ẹbọ mímọ́, tí àwọn ọmọ Israẹli ti yà sọ́tọ̀ fún èmi OLUWA, kinní bí àwo pẹrẹsẹ yìí yóo máa wà níwájú orí rẹ̀, kí wọ́n lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ mi. “Fi aṣọ ọ̀gbọ̀ tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí dá ẹ̀wù fún Aaroni, kí o fi aṣọ ọ̀gbọ̀ rán fìlà rẹ̀ pẹlu, lẹ́yìn náà rán àmùrè tí a ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára fún un. “Rán ẹ̀wù ati àmùrè, ati fìlà fún àwọn ọmọ Aaroni fún ògo ati ẹwà. Gbé àwọn ẹ̀wù náà wọ Aaroni arakunrin rẹ, ati àwọn ọmọ rẹ̀, kí o sì ta òróró sí wọn lórí láti yà wọ́n sọ́tọ̀ ati láti yà wọ́n sí mímọ́, kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ alufaa fún mi. Fi aṣọ ọ̀gbọ̀ dá ṣòkòtò fún wọn; láti máa fi bo ìhòòhò wọn, láti ìbàdí títí dé itan. Kí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ máa wọ ṣòkòtò náà, nígbà tí wọ́n bá wọ inú àgọ́ àjọ lọ, tabi nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ ibi pẹpẹ láti ṣe iṣẹ́ alufaa ni ibi mímọ́, kí wọ́n má baà dẹ́ṣẹ̀, kí wọ́n sì kú. Títí laelae ni òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ yóo máa pa ìlànà yìí mọ́. “Ohun tí o óo ṣe láti ya Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ sọ́tọ̀ kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ alufaa fún mi nìyí: mú ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù kan, ati àgbò meji tí kò ní àbùkù, mú burẹdi tí kò ní ìwúkàrà, ati àkàrà dídùn tí kò ní ìwúkàrà tí a fi òróró pò, ati burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí kò ní ìwúkàrà, tí a da òróró sí lórí. Ìyẹ̀fun kíkúnná ni kí o fi ṣe wọ́n. Kó àwọn burẹdi ati àkàrà náà sinu agbọ̀n kan, gbé wọn wá pẹlu akọ mààlúù ati àgbò mejeeji náà. “Mú Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ, kí o sì fi omi wẹ̀ wọ́n. Lẹ́yìn náà, kó àwọn aṣọ náà, wọ Aaroni lẹ́wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, ati ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ efodu, ati efodu náà, ati ìgbàyà. Lẹ́yìn náà, fi ọ̀já efodu tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí dì í ní àmùrè. Fi fìlà náà dé e lórí, kí o sì gbé adé mímọ́ lé orí fìlà náà. Gbé òróró ìyàsọ́tọ̀, kí o dà á lé e lórí láti yà á sọ́tọ̀. “Kó àwọn ọmọ rẹ̀ wá, kí o sì wọ̀ wọ́n lẹ́wù, dì wọ́n lámùrè, kí o sì dé wọn ní fìlà. Bẹ́ẹ̀ ni kí o ṣe ya Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ sí mímọ́, atọmọdọmọ wọn yóo sì máa ṣe alufaa mi. “Lẹ́yìn náà, mú akọ mààlúù náà wá siwaju àgọ́ àjọ, kí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ọwọ́ lé akọ mààlúù náà lórí. Lẹ́yìn náà, pa akọ mààlúù náà níwájú OLUWA lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ àjọ. Gbà ninu ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù náà, kí o fi ìka rẹ tọ́ ọ sí ara ìwo pẹpẹ, kí o sì da ìyókù rẹ̀ sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ. Fá gbogbo ọ̀rá tí ó bo ìfun, ati ẹ̀dọ̀ akọ mààlúù náà; mú kíndìnrín rẹ̀ mejeeji, ati ọ̀rá tí ó bò wọ́n; kí o sun wọ́n lórí pẹpẹ náà. Ṣugbọn lẹ́yìn ibùdó ni kí o ti fi iná sun ẹran ara rẹ̀, ati awọ rẹ̀, ati nǹkan inú rẹ̀, nítorí pé, ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni. “Lẹ́yìn náà, mú ọ̀kan ninu àwọn àgbò mejeeji, kí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ọwọ́ lé e lórí. Lẹ́yìn náà, pa àgbò náà, sì gba ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, kí o dà á sí ara pẹpẹ yíká. Gé ẹran àgbò náà sí wẹ́wẹ́, kí o fọ àwọn nǹkan inú rẹ̀ ati ẹsẹ̀ rẹ̀. Dà wọ́n mọ́ àwọn tí o gé wẹ́wẹ́ ati orí rẹ̀, kí o sì sun gbogbo wọn lórí pẹpẹ, ẹbọ sísun olóòórùn dídùn ni sí OLUWA, àní ẹbọ tí a fi iná sun. “Lẹ́yìn náà, mú àgbò keji, kí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ọwọ́ lé e lórí. Pa àgbò náà, kí o sì gbà ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kí o tọ́ ọ sí etí ọ̀tún Aaroni ati ti àwọn ọmọ rẹ̀, ati sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, ati sí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún wọn pẹlu. Lẹ́yìn náà, da ẹ̀jẹ̀ yòókù sí ara pẹpẹ yíká. Mú lára ẹ̀jẹ̀ tí ó wà lára pẹpẹ, sì mú ninu òróró tí wọ́n máa ń ta sí ni lórí, kí o wọ́n ọn sí Aaroni lórí ati sí ara ẹ̀wù rẹ̀, ati sí orí àwọn ọmọ rẹ̀, ati sí ara ẹ̀wù wọn. Òun ati ẹ̀wù rẹ̀ yóo di mímọ́, àwọn ọmọ rẹ̀ ati ẹ̀wù wọn yóo sì di mímọ́ pẹlu. “Mú ọ̀rá àgbò náà ati ìrù rẹ̀ tòun tọ̀rá rẹ̀, ati gbogbo ọ̀rá tí ó bo ìfun ati èyí tí ó bo ẹ̀dọ̀; ati kíndìnrín rẹ̀ mejeeji, pẹlu ọ̀rá tí ó bò wọ́n ati itan rẹ̀ ọ̀tún, nítorí àgbò ìyàsímímọ́ ni. Mú burẹdi kan, àkàrà dídùn kan pẹlu òróró, ati burẹdi pẹlẹbẹ láti inú agbọ̀n burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, tí ó wà níwájú OLUWA. Kó gbogbo wọn lé Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, kí wọ́n sì fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì níwájú OLUWA. Lẹ́yìn náà, gba gbogbo àkàrà náà lọ́wọ́ wọn, kí o fi iná sun wọ́n lórí pẹpẹ pẹlu ẹbọ sísun olóòórùn dídùn níwájú OLUWA, ẹbọ tí a fi iná sun sí OLUWA ni. “Mú igẹ̀ àgbò tí a fi ya Aaroni sí mímọ́, kí o sì fì í gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA, èyí ni yóo jẹ́ ìpín tìrẹ. “O óo ya igẹ̀ ẹbọ fífì náà sí mímọ́ ati itan tí ó jẹ́ ti àwọn alufaa lára àgbò ìyàsímímọ́, nítorí pé, ti Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni. Yóo máa jẹ́ ìpín ìran wọn títí lae, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli yóo ṣe máa fún àwọn alufaa lára ẹbọ alaafia wọn; ẹbọ wọn sí OLUWA ni. “Ẹ̀wù mímọ́ Aaroni yóo di ti arọmọdọmọ rẹ̀ lẹ́yìn ikú rẹ̀, àwọn aṣọ mímọ́ náà ni wọn yóo máa wọ̀; wọn yóo máa wọ̀ wọ́n nígbà tí wọ́n bá fi àmì òróró yàn wọ́n, tí wọ́n sì yà wọ́n sí mímọ́. Èyíkéyìí ninu àwọn ọmọ rẹ̀ tí ó bá di alufaa dípò rẹ̀ yóo wọ àwọn aṣọ wọnyi fún ọjọ́ meje, nígbà tí ó bá wá sí ibi àgọ́ àjọ. “Mú àgbò ìyàsímímọ́ náà, kí o sì bọ ẹran ara rẹ̀ ní ibi mímọ́ kan. Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ yóo sì jẹ ẹran àgbò náà, ati burẹdi tí ó wà ninu agbọ̀n, ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ. Wọn yóo jẹ àwọn nǹkan tí wọ́n fi ṣe ètùtù láti yà wọ́n sọ́tọ̀ ati láti yà wọ́n sí mímọ́, eniyan tí kì í bá ṣe alufaa kò gbọdọ̀ jẹ ninu rẹ̀, nítorí pé mímọ́ ni wọ́n. Bí ẹran ìyàsímímọ́ ati burẹdi náà bá kù di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, fi iná sun ìyókù, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́ nítorí pé mímọ́ ni. “Bẹ́ẹ̀ ni kí o ṣe sí Aaroni, ati àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí mo ti pa á láṣẹ fún ọ; ọjọ́ meje ni kí o fi yà wọ́n sí mímọ́. Lojoojumọ ni kí o máa fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan, rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ètùtù. O sì níláti máa rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún pẹpẹ náà nígbà tí o bá ń ṣe ètùtù fún un, ta òróró sí i láti yà á sí mímọ́. Ọjọ́ meje ni o níláti fi ṣe ètùtù fún pẹpẹ, kí o sì yà á sí mímọ́, nígbà náà ni pẹpẹ náà yóo di mímọ́, ohunkohun tí ó bá sì kan pẹpẹ náà yóo di mímọ́ pẹlu. “Ohun tí o óo máa fi rú ẹbọ lórí pẹpẹ lojoojumọ ni: ọ̀dọ́ aguntan meji, tí ó jẹ́ ọlọ́dún kan. Fi ọ̀dọ́ aguntan kan rúbọ ní òwúrọ̀, sì fi ekeji rúbọ ní àṣáálẹ́. Ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, tí a pò pọ̀ mọ́ idamẹrin òṣùnwọ̀n hini ojúlówó epo olifi, ni kí o fi rúbọ pẹlu àgbò kinni, pẹlu idamẹrin òṣùnwọ̀n hini ọtí waini fún ìtasílẹ̀. Àṣaálẹ́ ni kí o fi ọ̀dọ́ aguntan keji rúbọ, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ọtí waini fún ìtasílẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ti òwúrọ̀. Ẹbọ olóòórùn dídùn ni, àní ẹbọ tí a fi iná sun sí OLUWA. Atọmọdọmọ yín yóo máa rúbọ sísun náà nígbà gbogbo lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ àjọ, níwájú OLUWA, níbi tí n óo ti máa bá yín pàdé, tí n óo sì ti máa bá yín sọ̀rọ̀. Ibẹ̀ ni n óo ti máa bá àwọn eniyan Israẹli pàdé, ògo mi yóo sì máa ya ibẹ̀ sí mímọ́. N óo ya àgọ́ àjọ ati pẹpẹ náà sí mímọ́, ati Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ pẹlu, kí wọ́n lè máa sìn mí gẹ́gẹ́ bí alufaa. N óo máa wà láàrin àwọn eniyan Israẹli, n óo sì máa jẹ́ Ọlọrun wọn. Wọn yóo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn, ẹni tí ó mú wọn jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti, kí n lè máa gbé ààrin wọn. Èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn. “Fi igi akasia tẹ́ pẹpẹ kan, tí wọn yóo máa sun turari lórí rẹ̀. Kí gígùn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan, fífẹ̀ rẹ̀ yóo sì jẹ́ igbọnwọ kan. Ìbú ati òòró rẹ̀ yóo rí bákan náà, yóo sì ga ní igbọnwọ meji, àṣepọ̀ mọ́ ìwo rẹ̀ ni kí o ṣe é. Fi ojúlówó wúrà bo òkè, ati gbogbo ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ yíká, ati ìwo rẹ̀ pẹlu. Fi wúrà ṣe ìgbátí yí gbogbo etí rẹ̀ po. Lẹ́yìn náà, ṣe òrùka wúrà meji fún pẹpẹ náà, jó wọn mọ́ abẹ́ ìgbátí rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji, àwọn òrùka náà ni wọn yóo máa ti ọ̀pá bọ̀ nígbà tí wọ́n bá fẹ́ gbé pẹpẹ náà. Fi igi akasia ṣe àwọn ọ̀pá, kí o sì yọ́ wúrà bò wọ́n. Gbé e sílẹ̀ lóde aṣọ títa tí ó wà lẹ́bàá àpótí ẹ̀rí, lọ́gangan iwájú ìtẹ́ àánú tí ó wà lókè àpótí ẹ̀rí náà, níbi tí n óo ti máa ba yín pàdé. Kí Aaroni máa sun turari olóòórùn dídùn lórí rẹ̀, ní àràárọ̀, nígbà tí ó bá ń tọ́jú àwọn fìtílà. Nígbà tí ó bá ń gbé àwọn fìtílà náà sí ààyè wọn ní àṣáálẹ́, yóo máa sun turari náà pẹlu, títí lae ni yóo máa sun turari náà níwájú OLUWA ní ìrandíran yín. Ẹ kò gbọdọ̀ sun turari tí ó jẹ́ aláìmọ́ lórí pẹpẹ náà, ẹ kò sì gbọdọ̀ sun ẹbọ sísun lórí rẹ̀; tabi ẹbọ oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ ta ohun mímu sílẹ̀ fún ètùtù lórí rẹ̀. Aaroni yóo máa ṣe ètùtù lórí àwọn ìwo rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́dún. Ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni yóo máa fi ṣe ètùtù náà lórí rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́dún ní ìrandíran yín. Pẹpẹ náà yóo jẹ́ ohun èlò tí ó mọ́ jùlọ fún OLUWA.” OLUWA sọ fún Mose pé, “Nígbà tí o bá ka iye àwọn eniyan Israẹli, ẹnìkọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ mú ohun ìràpadà ẹ̀mí rẹ̀ wá fún OLUWA, kí àjàkálẹ̀ àrùn má baà bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn, nígbà tí o bá kà wọ́n. Ohun tí ẹnìkọ̀ọ̀kan tí o bá kà yóo san ni: ìdajì ṣekeli, tí a fi ìwọ̀n ilé OLUWA wọ̀n, (tí ó jẹ́ ogún ìwọ̀n gera fún ìwọ̀n ṣekeli kan), ìdajì ṣekeli náà yóo sì jẹ́ ti OLUWA. Ẹnikẹ́ni tí a bá kà ní àkókò ìkànìyàn náà, tí ó bá tó ọmọ ogún ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó gbọdọ̀ san owó náà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fún OLUWA. Bí eniyan ti wù kí ó ní owó tó, kò gbọdọ̀ san ju ìdajì ṣekeli kan lọ; bí ó sì ti wù kí eniyan tòṣì tó, kò gbọdọ̀ san dín ní ìdajì ṣekeli kan, nígbà tí ẹ bá ń san ọrẹ OLUWA fún ìràpadà ẹ̀mí yín. Gba owó ètùtù lọ́wọ́ àwọn eniyan Israẹli, kí o sì máa lò ó fún iṣẹ́ ilé ìsìn àgọ́ àjọ, kí ó lè máa mú àwọn ọmọ Israẹli wá sí ìrántí níwájú OLUWA, kí ó sì lè jẹ́ ètùtù fún yín.” OLUWA tún wí fún Mose pé, “Fi idẹ ṣe agbada omi kan, kí ìdí rẹ̀ náà jẹ́ idẹ, gbé e sí ààrin àgọ́ àjọ ati pẹpẹ, kí o sì bu omi sinu rẹ̀. Omi yìí ni Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ yóo fi máa fọ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn. Nígbà tí wọ́n bá ń wọ àgọ́ àjọ lọ, tabi nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ ibi pẹpẹ láti ṣe iṣẹ́ alufaa wọn, láti rú ẹbọ sísun sí OLUWA; omi yìí ni wọ́n gbọdọ̀ fi fọ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn kí wọ́n má baà kú. Dandan ni kí wọ́n fọ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn, kí wọ́n má baà kú. Èyí yóo di ìlànà fún wọn títí lae: fún òun ati arọmọdọmọ rẹ̀ ní gbogbo ìran wọn.” Lẹ́yìn náà, OLUWA tún wí fún Mose pé, “Mú ojúlówó àwọn nǹkan olóòórùn dídùn wọnyi kí o kó wọn jọ: ẹẹdẹgbẹta (500) ìwọ̀n ṣekeli òjíá olómi, ati aadọtaleerugba (250) ìwọ̀n ṣekeli sinamoni, ati aadọtaleerugba (250) ìwọ̀n ṣekeli igi olóòórùn dídùn kan tí ó dàbí èèsún, ati ẹẹdẹgbẹta (500) ìwọ̀n ṣekeli kasia, ìwọ̀n ṣekeli ilé OLUWA ni kí wọ́n lò láti wọ̀n wọ́n. Lẹ́yìn náà, mú ìwọ̀n hini ojúlówó òróró olifi kan. Pa gbogbo nǹkan wọnyi pọ̀, kí o fi ṣe òróró mímọ́ fún ìyàsímímọ́. Ṣe é bí àwọn ìpara olóòórùn dídùn, yóo jẹ́ òróró ìyàsímímọ́ fún OLUWA. Ta òróró yìí sí ara àgọ́ àjọ, ati sí ara àpótí ẹ̀rí, ati sí ara tabili, ati gbogbo àwọn ohun èlò orí rẹ̀, ati sí ara ọ̀pá fìtílà ati gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, ati sí ara pẹpẹ turari, ati sí ara pẹpẹ ẹbọ sísun, ati gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, ati sí ara agbada omi, ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Fi yà wọ́n sí mímọ́, kí wọ́n lè jẹ́ mímọ́ patapata; ohunkohun tí ó bá kàn wọ́n yóo sì di mímọ́. Ta òróró yìí sí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ lórí, kí o fi yà wọ́n sí mímọ́; kí wọ́n lè máa ṣe alufaa fún mi. Sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, ‘Òróró yìí ni yóo jẹ́ òróró ìyàsímímọ́ ní ìrandíran yín, ẹ kò gbọdọ̀ dà á sí ara àwọn eniyan lásán, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe òróró mìíràn tí ó dàbí rẹ̀. Mímọ́ ni, ẹ sì gbọdọ̀ kà á sí mímọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe irú rẹ̀, tabi ẹnikẹ́ni tí ó bá dà á sórí ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe alufaa, a óo yọ olúwarẹ̀ kúrò lára àwọn eniyan rẹ̀.’ ” OLUWA wí fún Mose pé, “Mú àwọn ohun ìkunra olóòórùn dídùn wọnyi: sitakite, ati onika, ati galibanumi ati ojúlówó turari olóòórùn dídùn, gbogbo wọn gbọdọ̀ jẹ́ ìwọ̀n kan náà. Lọ̀ wọ́n pọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn tí wọn ń ṣe turari, kí o fi iyọ̀ sí i; yóo sì jẹ́ mímọ́. Bù ninu rẹ̀, kí o gún un lúbúlúbú. Lẹ́yìn náà, bù díẹ̀ ninu lúbúlúbú yìí, kí o fi siwaju àpótí ẹ̀rí ninu àgọ́ àjọ, níbi tí n óo ti bá ọ pàdé, yóo jẹ́ mímọ́ fún yín. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe irú turari náà fún ara yín, ṣugbọn ẹ mú un gẹ́gẹ́ bí ohun mímọ́ tí a yà sọ́tọ̀ fún OLUWA. Bí ẹnikẹ́ni bá ṣe irú rẹ̀, láti máa lò ó gẹ́gẹ́ bíi turari, a óo yọ olúwarẹ̀ kúrò lára àwọn eniyan rẹ̀.” OLUWA sọ fún Mose pé, “Wò ó, mo ti pe Besaleli ọmọ Uri, ọmọ ọmọ Huri, láti inú ẹ̀yà Juda. Mo sì ti fi ẹ̀mí Ọlọrun kún inú rẹ̀, mo ti fún un ní òye ati ọgbọ́n ati ìmọ̀ iṣẹ́ ọnà, láti fi wúrà ati fadaka ati idẹ ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà, láti dá oríṣìíríṣìí àrà sí ara òkúta ati láti tò ó, láti gbẹ́ igi ati láti fi oríṣìíríṣìí ohun èlò ṣe iṣẹ́ ọnà. Mo ti yan Oholiabu ọmọ Ahisamaki láti inú ẹ̀yà Dani pẹlu rẹ̀. Mo sì ti fún gbogbo àwọn oníṣẹ́ ọnà ní ọgbọ́n, kí wọ́n lè ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ. Ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ lórí àgọ́ àjọ, ati àpótí ẹ̀rí ati ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí rẹ̀, ati gbogbo àwọn ohun èlò àgọ́, ati tabili, ati gbogbo àwọn ohun èlò tí wọn yóo máa lò pẹlu rẹ̀, ọ̀pá fìtílà tí wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe, ati gbogbo àwọn ohun èlò tí wọn yóo máa lò pẹlu rẹ̀, pẹpẹ turari, pẹpẹ ẹbọ sísun ati gbogbo ohun èlò tí wọn yóo máa lò pẹlu rẹ̀ ati agbada omi ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀; ati àwọn ẹ̀wù tí a dárà sí, ẹ̀wù mímọ́ Aaroni alufaa ati ẹ̀wù àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọn yóo máa fi ṣe iṣẹ́ alufaa wọn, ati òróró ìyàsímímọ́, ati turari olóòórùn dídùn fún ibi mímọ́. Gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ patapata ni wọn yóo ṣe bí mo ti pa á láṣẹ.” OLUWA rán Mose, ó ní, “Sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, ‘Ẹ pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, nítorí pé òun ni àmì tí ó wà láàrin èmi pẹlu yín ní ìrandíran yín; kí ẹ lè mọ̀ pé, èmi OLUWA yà yín sọ́tọ̀ fún ara mi. Ẹ máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ nítorí pé ọjọ́ mímọ́ ni fún yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọ́ di aláìmọ́, pípa ni kí wọ́n pa á; ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan ní ọjọ́ náà, a óo yọ ọ́ kúrò lára àwọn eniyan rẹ̀. Ọjọ́ mẹfa ni kí ẹ máa fi ṣiṣẹ́, ọjọ́ keje jẹ́ ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀, èyí tí ó jẹ́ mímọ́ fún OLUWA. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan ní ọjọ́ ìsinmi, pípa ni kí wọ́n pa á. Nítorí náà, àwọn eniyan Israẹli yóo máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, wọn yóo máa ranti rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àmì majẹmu ní ìrandíran wọn. Ọjọ́ náà jẹ́ àmì ayérayé tí ó wà láàrin èmi ati àwọn eniyan Israẹli, pé ọjọ́ mẹfa ni èmi Ọlọrun fi dá ọ̀run ati ayé, ati pé ní ọjọ́ keje, mo dáwọ́ iṣẹ́ ṣíṣe dúró, mo sì sinmi.’ ” Nígbà tí Ọlọrun bá Mose sọ̀rọ̀ tán lórí òkè Sinai, ó fún un ní wàláà òkúta meji gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí. Ọlọrun fúnra rẹ̀ ni ó fi ìka ara rẹ̀ kọ ohun tí ó wà lára àwọn wàláà náà. Nígbà tí àwọn eniyan náà rí i pé Mose ń pẹ́ jù lórí òkè, wọ́n kó ara wọn jọ, wọ́n tọ Aaroni lọ; wọ́n sọ fún un pé, “Ṣe oriṣa kan fún wa, tí yóo máa ṣáájú wa lọ; nítorí pé, a kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Mose tí ó kó wa wá láti ilẹ̀ Ijipti.” Aaroni bá sọ fún wọn pé, “Ẹ gba gbogbo yẹtí wúrà etí àwọn aya yín jọ, ati ti àwọn ọmọkunrin yín, ati ti àwọn ọmọbinrin yín, kí ẹ sì kó wọn wá.” Gbogbo àwọn eniyan náà bá bọ́ yẹtí wúrà etí wọn jọ, wọ́n kó wọn tọ Aaroni lọ. Aaroni gba wúrà náà lọ́wọ́ wọn, ó lo irinṣẹ́ àwọn alágbẹ̀dẹ, ó fi wúrà náà da ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù kan. Àwọn eniyan náà bá dáhùn pé, “Ẹ̀yin eniyan Israẹli, ọlọrun yín tí ó mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti nìyí.” Nígbà tí Aaroni rí i bẹ́ẹ̀, ó tẹ́ pẹpẹ kan siwaju ère náà, ó sì kéde pé, “Ọ̀la yóo jẹ́ ọjọ́ àjọ fún OLUWA.” Wọ́n dìde ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, wọ́n rú ẹbọ sísun, wọ́n sì mú ẹbọ alaafia wá, wọ́n bá jókòó, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì ń ṣe àríyá tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn lòpọ̀. OLUWA wí fún Mose pé, “Tètè sọ̀kalẹ̀, nítorí pé àwọn eniyan rẹ tí o kó ti ilẹ̀ Ijipti wá ti ba ara wọn jẹ́. Wọ́n ti yipada kúrò ní ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fún wọn, wọ́n ti yá ère mààlúù kan, wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí bọ ọ́, wọ́n sì ti ń rúbọ sí i. Wọ́n ń wí pé, ‘ọlọ́run yín nìyí Israẹli, ẹni tí ó mú yín gòkè wá láti ilẹ̀ Ijipti.’ ” OLUWA bá wí fún Mose pé, “Mo ti rí àwọn eniyan wọnyi, wò ó, alágídí ni wọ́n. Dá mi dá wọn, inú ń bí mi sí wọn gidigidi, píparẹ́ ni n óo sì pa wọ́n rẹ́, ṣugbọn n óo sọ ìwọ di orílẹ̀-èdè ńlá.” Ṣugbọn Mose bẹ OLUWA Ọlọrun rẹ̀, ó ní, “OLUWA, kí ló dé tí inú fi bí ọ tóbẹ́ẹ̀ sí àwọn eniyan rẹ, àwọn tí o fi agbára ati tipátipá kó jáde láti ilẹ̀ Ijipti? Kí ló dé tí o óo fi jẹ́ kí àwọn ará Ijipti wí pé, o mọ̀ọ́nmọ̀ fẹ́ ṣe wọ́n níbi ni o fi kó wọn jáde láti pa wọ́n lórí òkè yìí, ati láti pa wọ́n rẹ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé? Jọ̀wọ́, má bínú mọ, yí ọkàn rẹ pada, má sì ṣe ibi tí o ti pinnu láti ṣe sí àwọn eniyan rẹ. Wo ti Abrahamu, ati Isaaki, ati Israẹli, àwọn iranṣẹ rẹ, àwọn tí o ti fi ara rẹ búra fún pé o ó sọ arọmọdọmọ wọn di pupọ gẹ́gẹ́ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run; o ní gbogbo ilẹ̀ tí o ti ṣèlérí ni o óo fi fún àwọn arọmọdọmọ wọn; ati pé àwọn ni wọn yóo sì jogún rẹ̀ títí lae.” Ọlọrun bá yí ọkàn rẹ̀ pada, kò sì ṣe ibi tí ó gbèrò láti ṣe sí àwọn eniyan náà mọ́. Mose bá yipada, ó sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, tòun ti wàláà òkúta ẹ̀rí mejeeji lọ́wọ́ rẹ̀, àwọn wàláà òkúta tí Ọlọrun ti kọ nǹkan sí lójú mejeeji. Iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọrun ni àwọn wàláà òkúta náà, Ọlọrun tìkararẹ̀ ni ó sì fi ọwọ́ ara rẹ̀ kọ ohun tí ó wà lára wọn. Bí Joṣua ti gbọ́ ariwo àwọn eniyan náà tí wọn ń ké, ó wí fún Mose pé, “Ariwo ogun wà ninu àgọ́.” Ṣugbọn Mose dáhùn pé, “Èyí kì í ṣe ìhó ìṣẹ́gun, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe igbe ẹni tí wọ́n ṣẹgun rẹ̀, ìró orin ni èyí tí mò ń gbọ́ yìí.” Bí ó ti súnmọ́ tòsí àgọ́, bẹ́ẹ̀ ni ó rí ère ọmọ mààlúù, ó sì rí àwọn eniyan tí wọn ń jó. Inú bí Mose gidigidi tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi ju àwọn wàláà òkúta náà mọ́lẹ̀, ó sì fọ́ wọn ní ẹsẹ̀ òkè náà. Ó mú ère ọmọ mààlúù náà, tí wọ́n fi wúrà ṣe, ó sun ún níná, ó lọ̀ ọ́ lúbúlúbú, ó kù ú sójú omi, ó sì gbé e fún àwọn ọmọ Israẹli mu. Mose bi Aaroni pé, “Kí ni àwọn eniyan wọnyi fi ṣe ọ́, tí o fi mú ẹ̀ṣẹ̀ ńláńlá yìí wá sórí wọn?” Aaroni bá dáhùn, ó ní, “Má bínú, oluwa mi, ṣebí ìwọ náà mọ àwọn eniyan wọnyi pé eeyankeeyan ni wọ́n, àwọn ni wọ́n wá bá mi tí wọ́n ní, ‘Ṣe oriṣa fún wa tí yóo máa ṣáájú wa lọ, nítorí pé a kò mọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí Mose, tí ó kó wa wá láti ilẹ̀ Ijipti.’ Ni mo bá wí fún wọn pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ní wúrà, kí ó bọ́ ọ wá.’ Wọ́n kó wọn fún mi, ni mo bá dà wọ́n sinu iná, òun ni mo sì fi yá ère mààlúù yìí.” Nígbà tí Mose rí i pé Aaroni ti dá rúdurùdu sílẹ̀, láàrin àwọn eniyan náà, ati pé apá kò ká wọn mọ́, ọ̀rọ̀ náà sì sọ wọ́n di ẹni ìtìjú níwájú àwọn ọ̀tá wọn, Mose bá dúró ní ẹnu ọ̀nà àgọ́, ó ní, “Ẹ̀yin wo ni ẹ̀ ń ṣe ti OLUWA, ẹ máa bọ̀ lọ́dọ̀ mi.” Gbogbo àwọn ọmọ Lefi bá kóra jọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Mose wí fún wọn pé, “Ẹ gbọ́ bí OLUWA Ọlọrun Israẹli ti wí, ó ní, ‘Gbogbo ẹ̀yin ọkunrin, ẹ sán idà yín mọ́ ẹ̀gbẹ́ yín kí ẹ sì máa lọ láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà, jákèjádò ibùdó, kí olukuluku máa pa arakunrin rẹ̀ ati ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ati aládùúgbò rẹ̀.’ ” Àwọn ọmọ Lefi sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Mose ti wí, àwọn tí wọ́n kú láàrin àwọn eniyan náà tó ẹgbẹẹdogun (3,000) ọkunrin. Mose bá wí fún wọn pé, “Lónìí ni ẹ yan ara yín fún iṣẹ́ OLUWA, olukuluku yín sì ti fi ẹ̀mí ọmọ rẹ̀, ati ti arakunrin rẹ̀ yan ara rẹ̀, kí ó lè tú ibukun rẹ̀ sí orí yín lónìí yìí.” Ní ọjọ́ keji, Mose wí fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ ti dẹ́ṣẹ̀ ńlá, n óo tún gòkè tọ OLUWA lọ, bóyá n óo lè ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yín.” Mose bá pada tọ OLUWA lọ, ó ní, “Yéè! Àwọn eniyan wọnyi ti dẹ́ṣẹ̀ ńlá; wọ́n ti fi wúrà yá ère fún ara wọn; ṣugbọn OLUWA, jọ̀wọ́, dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, pa orúkọ mi rẹ́ patapata kúrò ninu ìwé tí o kọ orúkọ àwọn eniyan rẹ sí.” OLUWA bá dá Mose lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá dẹ́ṣẹ̀ sí mi ni n óo pa orúkọ rẹ̀ rẹ́ kúrò ninu ìwé mi. Pada lọ nisinsinyii, kí o sì kó àwọn eniyan náà lọ sí ibi tí mo sọ fún ọ. Ranti pé angẹli mi yóo máa ṣáájú yín lọ, ṣugbọn ọjọ́ ń bọ̀, tí n óo jẹ àwọn eniyan náà níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” Nítorí náà, nígbà tó yá, Ọlọrun rán àjàkálẹ̀ àrùn burúkú kan sáàrin àwọn eniyan náà, nítorí pé wọ́n mú kí Aaroni fi wúrà yá ère mààlúù fún wọn. OLUWA tún pe Mose, ó ní, “Dìde kúrò níhìn-ín, ìwọ ati àwọn eniyan tí o kó wá láti ilẹ̀ Ijipti, ẹ lọ sí ilẹ̀ tí mo ti búra fún Abrahamu, ati fún Isaaki, ati fún Jakọbu pé n óo fún arọmọdọmọ wọn. N óo rán angẹli mi ṣáájú yín, n óo sì lé àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Hamori, àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi ati àwọn ará Jebusi jáde. Ẹ lọ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá náà, tí ó kún fún wàrà ati oyin; n kò ní sí ní ààrin yín nígbà tí ẹ bá ń lọ, nítorí orí kunkun yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ n óo pa yín run lójú ọ̀nà.” Nígbà tí àwọn eniyan gbọ́ ìròyìn burúkú náà, ọkàn wọn bàjẹ́, kò sì sí ẹni tí ó fi ohun ọ̀ṣọ́ sí ara rárá. Nítorí náà, OLUWA rán Mose pé kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé olóríkunkun ni wọ́n, ati pé bí òun bá sọ̀kalẹ̀ sí ààrin wọn ní ìṣẹ́jú kan, òun yóo pa wọ́n run; nítorí náà, kí wọ́n kó gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ wọn kúrò, kí òun lè mọ ohun tí òun yóo fi wọ́n ṣe. Nítorí náà, àwọn ọmọ Israẹli bọ́ gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ wọn kúrò, ní òkè Horebu. Mose a máa pa àgọ́ àjọ sí òkèèrè, lẹ́yìn ibùdó àwọn ọmọ Israẹli, ó sì sọ ọ́ ní àgọ́ àjọ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ní ohunkohun láti bèèrè lọ́dọ̀ OLUWA yóo lọ sí ibi àgọ́ àjọ náà, tí ó wà lẹ́yìn ibùdó àwọn ọmọ Israẹli. Nígbàkúùgbà tí Mose bá ń lọ sí ibi àgọ́ àjọ, olukuluku á dúró lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ rẹ̀, wọn a sì máa wò ó títí yóo fi wọ inú àgọ́ àjọ lọ. Bí Mose bá ti wọ inú àgọ́ àjọ náà lọ, ìkùukùu náà á sọ̀kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òpó, a sì dúró lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ náà. OLUWA yóo sì bá Mose sọ̀rọ̀. Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan bá sì rí ìkùukùu tí ó dàbí òpó yìí, lẹ́nu ọ̀nà àgọ́, gbogbo àwọn eniyan á dìde, olukuluku wọn á sì sin OLUWA ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe máa ń bá Mose sọ̀rọ̀ ní ojúkoojú, bí eniyan ṣe ń bá ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Nígbà tí Mose bá pada sí ibùdó, Joṣua, iranṣẹ rẹ̀, ọmọ Nuni, tí òun jẹ́ ọdọmọkunrin, kìí kúrò ninu àgọ́ àjọ. Mose bá wí fún OLUWA pé, “Ṣebí ìwọ OLUWA ni o sọ pé kí n kó àwọn eniyan wọnyi wá, ṣugbọn o kò tíì fi ẹni tí o óo rán ṣìkejì mi hàn mí. Sibẹsibẹ, o wí pé, o mọ̀ mí o sì mọ orúkọ mi, ati pé mo ti rí ojurere rẹ. Nítorí náà, mo bẹ̀ ọ́, bí inú rẹ bá dùn sí mi, fi ọ̀nà rẹ hàn mí, kí n lè mọ̀ ọ́, kí ǹ sì lè bá ojurere rẹ pàdé. Sì ranti pé àwọn eniyan rẹ ni àwọn eniyan wọnyi.” OLUWA bá dá a lóhùn pé, “Ojú mi yóo máa bá ọ lọ, n óo sì fún ọ ní ìsinmi.” Mose wí fún OLUWA pé, “Bí o kò bá ní bá wa lọ, má wulẹ̀ kó wa kúrò níhìn-ín. Nítorí pé, báwo ni àwọn eniyan yóo ṣe mọ̀ pé, inú rẹ dùn sí èmi ati àwọn eniyan rẹ? Ṣebí bí o bá wà pẹlu wa bí a ti ń lọ ni a óo fi lè dá èmi ati àwọn eniyan rẹ mọ̀ yàtọ̀ sí gbogbo aráyé yòókù.” OLUWA dá Mose lóhùn pé, “N óo ṣe ohun tí o wí, nítorí pé inú mi dùn sí ọ, mo sì mọ orúkọ rẹ.” Mose dáhùn pé, “Mo bẹ̀ ọ́, fi ògo rẹ hàn mí.” OLUWA sì dá Mose lóhùn pé, “N óo mú kí ẹwà mi kọjá níwájú rẹ; n óo sì pe orúkọ mímọ́ mi lójú rẹ, èmi ni OLUWA, èmi a máa yọ́nú sí àwọn tí ó bá wù mí, èmi a sì máa ṣàánú fún àwọn tí mo bá fẹ́.” OLUWA ní, “O kò lè rí ojú mi nítorí pé eniyan kò lè rí ojú mi kí ó wà láàyè.” OLUWA tún dáhùn pé, “Ibìkan wà, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀dọ̀ mi, wá dúró lórí òkúta kan níbẹ̀. Nígbà tí ògo mi bá ń kọjá lọ, n óo pa ọ́ mọ́ ninu ihò òkúta yìí, n óo sì fi ọwọ́ mi bò ọ́ lójú nígbà tí mo bá ń rékọjá. Lẹ́yìn náà, n óo ká ọwọ́ mi kúrò, o óo sì rí àkẹ̀yìnsí mi, ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò lè rí ojú mi.” Ọlọrun sọ fún Mose pé, “Gbẹ́ wàláà òkúta meji bíi ti àkọ́kọ́, n óo sì kọ àwọn ọ̀rọ̀ tí mo kọ sára wàláà ti àkọ́kọ́ tí ó fọ́ sára wọn. Múra ní àárọ̀ ọ̀la, kí o gun òkè Sinai wá, kí o wá farahàn mí lórí òkè náà. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ bá ọ wá, ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ sí níbikíbi lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè náà, àwọn mààlúù, tabi àwọn aguntan kò gbọdọ̀ jẹ káàkiri níbikíbi lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè náà.” Mose bá gbẹ́ wàláà òkúta meji gẹ́gẹ́ bíi ti àkọ́kọ́, ó gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu, ó gun òkè Sinai lọ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un; ó kó àwọn wàláà òkúta mejeeji náà lọ́wọ́. OLUWA tún sọ̀kalẹ̀ ninu ìkùukùu ó dúró níbẹ̀ pẹlu rẹ̀, ó sì pe orúkọ mímọ́ ara rẹ̀. OLUWA kọjá níwájú rẹ̀, ó sì kéde orúkọ ara rẹ̀ báyìí pé, “OLUWA Ọlọrun aláàánú ati olóore, ẹni tí ó lọ́ra láti bínú, tí ó sì pọ̀ ní àánú ati òtítọ́. Ẹni tí ó máa ń ṣàánú fún ẹgbẹẹgbẹrun, tí ó máa ń dárí àìṣedéédé ji eniyan, ó máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀, ati ìrékọjá jì, ṣugbọn kì í jẹ́ kí ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ láìjìyà, a sì máa fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ ati ọmọ ọmọ títí dé ìran kẹta ati ikẹrin.” Mose yára tẹ orí ba, ó dojú bolẹ̀, ó sì sin OLUWA. Ó ní, “Bí inú rẹ bá dùn sí mi nítòótọ́, OLUWA, jọ̀wọ́, máa wà láàrin wa, nígbà tí a bá ń lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé olóríkunkun ni àwọn eniyan náà; dárí ẹ̀ṣẹ̀ ati àìṣedéédé wa jì wá, kí o sì gbà wá gẹ́gẹ́ bí eniyan rẹ.” OLUWA wí fún Mose pé, “Mo dá majẹmu kan, n óo ṣe iṣẹ́ ìyanu níwájú àwọn eniyan náà, irú èyí tí ẹnikẹ́ni kò rí rí ní gbogbo ayé tabi láàrin orílẹ̀-èdè kankan. Gbogbo àwọn eniyan tí ẹ̀ ń gbé ààrin wọn yóo sì rí iṣẹ́ OLUWA, nítorí ohun tí n óo ṣe fún wọn yóo bani lẹ́rù jọjọ. “Máa pa àwọn òfin tí mo fún ọ lónìí yìí mọ́. N óo lé àwọn ará Hamori ati àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti ati àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi ati àwọn ará Jebusi, jáde kúrò níwájú rẹ. Ẹ ṣọ́ra gidigidi, kí ẹ rí i pé ẹ kò bá àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ dá majẹmu kankan, kí wọn má baà dàbí tàkúté tí a dẹ sí ààrin yín. Ṣugbọn, ẹ wó gbogbo pẹpẹ wọn, kí ẹ sì fọ́ gbogbo àwọn ère wọn, kí ẹ sì gé gbogbo igbó oriṣa wọn lulẹ̀. “Ẹ kò gbọdọ̀ bọ oriṣa, nítorí èmi OLUWA, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ owú, Ọlọrun tíí máa jowú ni mí. Ẹ kò gbọdọ̀ bá ẹnikẹ́ni dá majẹmu ninu gbogbo àwọn eniyan tí ń gbé ilẹ̀ náà, kí ẹ má baà bá wọn dá majẹmu tán, kí ó wá di pé, nígbà tí wọn bá ń rúbọ sí oriṣa wọn, tí wọn sì ń ṣe ìṣekúṣe nídìí oriṣa wọn, wọn óo máa pè yín, pé kí ẹ máa lọ bá wọn jẹ ninu ẹbọ wọn. Kó má baà wá di pé ẹ̀ ń fẹ́mọ lọ́wọ́ wọn fún àwọn ọmọkunrin yín, kí àwọn ọmọbinrin yín má baà máa ṣe ìṣekúṣe nídìí oriṣa, kí wọ́n sì mú kí àwọn ọmọkunrin yín náà máa ṣe ìṣekúṣe nídìí oriṣa wọn. “Ẹ kò gbọdọ̀ yá ère fún ara yín. “Ẹ gbọdọ̀ máa ṣe àjọ àìwúkàrà, burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ni ẹ gbọdọ̀ máa jẹ fún ọjọ́ meje ní àkókò àjọ náà, ninu oṣù Abibu, gẹ́gẹ́ bí mo ti pàṣẹ fún yín, nítorí pé ninu oṣù Abibu ni ẹ jáde ní ilẹ̀ Ijipti. “Tèmi ni gbogbo ohun tí ó bá jẹ́ àkọ́bí, gbogbo àkọ́bí ẹran: kì báà jẹ́ ti mààlúù, tabi ti aguntan. Ṣugbọn ọ̀dọ́ aguntan ni kí ẹ máa fi ra àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yín tí ó bá jẹ́ akọ pada, tí ẹ kò bá fẹ́ rà á pada, ẹ gbọdọ̀ lọ́ ọ lọ́rùn pa. Gbogbo àkọ́bí yín lọkunrin, ni ẹ gbọdọ̀ rà pada. “Ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ wá siwaju mi ní ọwọ́ òfo láti sìn mí. “Ọjọ́ mẹfa ni kí ẹ fi ṣe iṣẹ́ yín, ní ọjọ́ keje ẹ gbọdọ̀ sinmi; kì báà ṣe àkókò oko ríro, tabi àkókò ìkórè, dandan ni kí ẹ sinmi. “Ẹ gbọdọ̀ máa ṣe àjọ̀dún ọ̀sẹ̀ ìkórè àkọ́so alikama ọkà yín, ati àjọ̀dún ìkójọ nígbà tí ẹ bá ń kórè nǹkan oko sinu abà ní òpin ọdún. “Ẹẹmẹta lọdọọdun, ni gbogbo àwọn ọmọkunrin yín gbọdọ̀ wá siwaju èmi OLUWA Ọlọrun, Ọlọrun Israẹli, kí wọ́n wá sìn mí. Nítorí pé n óo lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde fún yín, n óo sì fẹ ààlà yín sẹ́yìn. Kò sì ní sí ẹnikẹ́ni tí yóo fẹ́ gba ilẹ̀ yín nígbà tí ẹ bá lọ sin OLUWA Ọlọrun yín, lẹẹmẹtẹẹta lọdọọdun. “Ẹ kò gbọdọ̀ fi ẹran rúbọ sí mi pẹlu ìwúkàrà, bẹ́ẹ̀ ni ohunkohun tí ẹ bá sì fi rú ẹbọ àjọ̀dún ìrékọjá kò gbọdọ̀ kù di ọjọ́ keji. “Ẹ gbọdọ̀ mú àkọ́so oko yín wá sí ilé OLUWA Ọlọrun yín. “Ẹ kò gbọdọ̀ bọ ọmọ ẹran ninu omi ọmú ìyá rẹ̀.” OLUWA wí fún Mose pé, “Kọ ọ̀rọ̀ wọnyi sílẹ̀, nítorí pé òun ni majẹmu mi dúró lé lórí pẹlu ìwọ ati Israẹli.” Mose sì wà pẹlu OLUWA fún ogoji ọjọ́ tọ̀sán-tòru, kò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò mu, ó sì kọ ọ̀rọ̀ majẹmu náà, tíí ṣe òfin mẹ́wàá, sára àwọn wàláà òkúta náà. Nígbà tí Mose sọ̀kalẹ̀ pada ti orí òkè Sinai dé, pẹlu wàláà ẹ̀rí meji lọ́wọ́ rẹ̀, Mose kò mọ̀ pé ojú òun ń dán, ó sì ń kọ mànàmànà, nítorí pé ó bá Ọlọrun sọ̀rọ̀. Nígbà tí Aaroni, ati àwọn ọmọ Israẹli rí Mose, wọ́n ṣe akiyesi pé ojú rẹ̀ ń kọ mànàmànà, ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti súnmọ́ ọn. Ṣugbọn Mose pè wọ́n, Aaroni ati gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀. Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli súnmọ́ ọn, ó sì ṣe gbogbo ohun tí Ọlọrun bá a sọ lórí òkè Sinai lófin fún wọn. Lẹ́yìn tí Mose bá wọn sọ̀rọ̀ tán ó fi aṣọ ìbòjú bo ojú rẹ̀. Ṣugbọn nígbà tí Mose bá wọlé lọ, láti bá OLUWA sọ̀rọ̀, a máa mú aṣọ ìbòjú náà kúrò ní ojú títí yóo fi jáde, nígbà tí ó bá sì jáde, yóo sọ ohun tí OLUWA bá pa láṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe akiyesi ojú Mose, pé ó ń kọ mànàmànà; Mose a sì máa fi aṣọ ìbòjú bo ojú rẹ̀ títí yóo fi di ìgbà tí yóo tún wọ ilé lọ láti bá OLUWA sọ̀rọ̀. Mose pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, ó wí fún wọn pé, “Àwọn nǹkan tí OLUWA pa láṣẹ pé kí ẹ máa ṣe nìwọ̀nyí: Ọjọ́ mẹfa ni kí ẹ máa fi ṣiṣẹ́, ṣugbọn kí ẹ ya ọjọ́ keje sọ́tọ̀ fún OLUWA bí ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ náà, pípa ni kí ẹ pa á. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ dáná ní gbogbo ilé yín ní ọjọ́ ìsinmi.” Mose sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA pa láṣẹ, ó ní, ‘Ẹ gba ọrẹ jọ fún OLUWA láàrin ara yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́, lè mú ọrẹ wá fún OLUWA. Àwọn ọrẹ náà ni: wúrà, fadaka ati idẹ, aṣọ aláwọ̀ aró, ti aláwọ̀ elése àlùkò, ati aṣọ pupa, aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, ati irun ewúrẹ́; awọ àgbò tí wọ́n ṣe ní àwọ̀ pupa ati awọ ewúrẹ́, igi akasia, òróró ìtànná, àwọn èròjà fún òróró ìyàsímímọ́ ati fún turari olóòórùn dídùn, òkúta onikisi ati òkúta tí wọn yóo tò sí ara efodu ati sí ara aṣọ ìgbàyà.’ “Kí gbogbo ọkunrin tí ó bá mọ iṣẹ́ ọwọ́ ninu yín jáde wá láti ṣe àwọn nǹkan tí OLUWA pa láṣẹ wọnyi: àgọ́ àjọ, ati àwọn ìbòrí rẹ, àwọn ìkọ́ rẹ̀ ati àwọn àkànpọ̀ igi rẹ̀, àwọn ọ̀pá rẹ̀, àwọn òpó rẹ̀, ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn. Àpótí ẹ̀rí, ati àwọn ọ̀pá rẹ̀, ìtẹ́ àánú rẹ̀, ati aṣọ títa rẹ̀. Tabili, pẹlu àwọn ọ̀pá rẹ̀ ati gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀ pẹlu burẹdi ìfihàn orí rẹ̀. Ọ̀pá fìtílà fún iná títàn, ati àwọn ohun èlò tí ó jẹ mọ́ fìtílà rẹ̀ ati òróró fún iná títàn. Pẹpẹ turari, ati àwọn ọ̀pá rẹ̀ ati òróró ìyàsímímọ́, ati turari olóòórùn dídùn, ati àwọn aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà. Pẹpẹ ẹbọ sísun tòun ti ojú ààrò onídẹ rẹ̀, pẹlu àwọn ọ̀pá rẹ̀ ati àwọn ohun èlò tí ó jẹ mọ́ ti pẹpẹ ẹbọ, agbada omi ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Àwọn aṣọ títa ti àgbàlá ati àwọn òpó rẹ̀ ati ìtẹ́lẹ̀ àwọn òpó ati aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà. Àwọn èèkàn àgọ́, ati àwọn èèkàn àgbàlá pẹlu àwọn okùn wọn; àwọn aṣọ tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí fún ṣíṣe iṣẹ́ alufaa níbi mímọ́, ati àwọn ẹ̀wù mímọ́ fún Aaroni alufaa, ati ẹ̀wù iṣẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀, tí wọn yóo máa fi ṣe iṣẹ́ alufaa.” Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá túká lọ́dọ̀ Mose. Lẹ́yìn náà gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ náà wọ̀ lọ́kàn, tí ó sì jẹ lógún bẹ̀rẹ̀ sí pada wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, wọn ń mú ọrẹ wá fún kíkọ́ àgọ́ àjọ náà, ati gbogbo ohun tí wọn nílò fún àgọ́ náà, ati fún ẹ̀wù mímọ́ àwọn alufaa. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá, atọkunrin atobinrin, gbogbo àwọn tí ó tinú ọkàn wọn wá, wọ́n mú yẹtí wúrà wá, ati òrùka wúrà, ati ẹ̀gbà wúrà, ati oríṣìíríṣìí ohun èlò mìíràn tí wọ́n fi wúrà ṣe; olukuluku wọn mú ẹ̀bùn wúrà wá fún OLUWA. Gbogbo àwọn tí wọ́n ní aṣọ aláwọ̀ aró, tabi ti elése àlùkò, tabi aṣọ pupa, tabi aṣọ funfun, tabi irun ewúrẹ́, tabi awọ àgbò tí a ṣe ní pupa, tabi awọ ewúrẹ́, bẹ̀rẹ̀ sí kó wọn wá. Gbogbo àwọn tí wọ́n lè fi fadaka ati idẹ tọrẹ fún OLUWA ni wọ́n mú wọn wá, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn tí wọ́n ní igi akasia, tí ó wúlò náà mú wọn wá pẹlu. Gbogbo àwọn obinrin tí wọ́n mọ òwú ran ni wọ́n ran òwú tí wọ́n sì kó o wá: àwọn òwú aláwọ̀ aró, elése àlùkò, aláwọ̀ pupa, ati funfun tí wọ́n fi ń hun aṣọ onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́. Gbogbo àwọn obinrin tí ọ̀rọ̀ náà jẹ lógún, tí wọ́n sì mọ irun ewúrẹ́ ran, ni wọ́n ran án wá. Àwọn àgbààgbà mú òkúta onikisi wá ati òkúta tí wọn yóo tò sí ara efodu ati sí ara aṣọ ìgbàyà, ati oríṣìíríṣìí èròjà ati òróró ìtànná, ati ti ìyàsímímọ́, ati fún turari olóòórùn dídùn. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli lọkunrin ati lobinrin tí ọ̀rọ̀ náà jẹ lógún ni wọ́n mú ọrẹ àtinúwá wá fún OLUWA, láti fi ṣe iṣẹ́ tí OLUWA pa láṣẹ fún Mose. Mose wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “OLUWA fúnra rẹ̀ ti yan Besaleli ọmọ Uri, ọmọ ọmọ Huri, láti inú ẹ̀yà Juda. Ọlọrun ti fi ẹ̀mí rẹ̀ sinu rẹ̀, ó sì ti fún un ní ọgbọ́n, òye, ati ìmọ̀ ninu oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà, láti fi wúrà ati fadaka ati idẹ ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà; láti gé oríṣìíríṣìí òkúta iyebíye ati láti tò wọ́n, bẹ́ẹ̀ náà ni igi gbígbẹ́ ati oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà ṣíṣe. Ọlọrun sì ti mí ìmísí rẹ̀ sí i ninu láti kọ́ ẹlòmíràn, àtòun ati Oholiabu ọmọ Ahisamaki láti inú ẹ̀yà Dani. Ọlọrun ti fún wọn ní ìmọ̀ oríṣìíríṣìí iṣẹ́ tí àwọn oníṣọ̀nà máa ń ṣe, ati ti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà ati ti àwọn tí wọn ń ṣe iṣẹ́ ọnà sí ara aṣọ, ìbáà jẹ́ aṣọ aláwọ̀ aró, tabi ti elése àlùkò tabi aṣọ pupa tabi aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ tabi oríṣìí aṣọ mìíràn, gbogbo iṣẹ́ ọnà ni wọn yóo máa ṣe; kò sì sí iṣẹ́ ọnà tí wọn kò lè ṣe. “Kí Besaleli, ati Oholiabu ati olukuluku àwọn tí OLUWA fún ní ìmọ̀ ati òye, láti ṣe èyíkéyìí ninu iṣẹ́ tí ó jẹmọ́ kíkọ́ ilé mímọ́ náà, ṣe é bí OLUWA ti pa á láṣẹ gan-an.” Mose bá pe Besaleli ati Oholiabu, ati olukuluku àwọn tí OLUWA ti fún ní ìmọ̀ ati òye ati gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìfẹ́ sí iṣẹ́ náà láti wá bẹ̀rẹ̀ rẹ̀. Àwọn òṣìṣẹ́ náà gba gbogbo àwọn ọrẹ àtinúwá tí àwọn ọmọ Israẹli mú wá láti fi ṣe iṣẹ́ àgọ́ mímọ́ náà lọ́wọ́ Mose. Àwọn eniyan ṣá tún ń mú ọrẹ àtinúwá yìí tọ Mose lọ ní àràárọ̀. Wọ́n mú ọrẹ wá tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn tí wọn ń ṣe iṣẹ́ ibi mímọ́ náà tọ Mose lọ; wọ́n sọ fún un pé, “Ohun tí àwọn eniyan náà mú wá ti pọ̀ ju ohun tí a nílò láti fi ṣe iṣẹ́ tí OLUWA pa láṣẹ fún wa.” Mose bá pàṣẹ, wọ́n sì kéde yí gbogbo àgọ́ ká, pé kí ẹnikẹ́ni, kì báà ṣe ọkunrin, tabi obinrin, má wulẹ̀ ṣòpò láti mú ọrẹ wá fún kíkọ́ ibi mímọ́ náà mọ́. Wọ́n sì dá àwọn eniyan náà lẹ́kun pé kí wọ́n má mú ọrẹ wá mọ́; nítorí pé ohun tí wọ́n ti mú wá ti tó, ó tilẹ̀ ti pọ̀jù fún ohun tí wọ́n nílò láti fi ṣe iṣẹ́ náà. Àwọn tí wọ́n mọ iṣẹ́ jù lára àwọn òṣìṣẹ́ náà kọ́ ibi mímọ́ náà pẹlu aṣọ títa mẹ́wàá. Aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ati aṣọ ẹlẹ́pa ati elése àlùkò ati aṣọ pupa fòò ni wọ́n fi ṣe àwọn aṣọ títa náà, wọ́n sì ya àwòrán kerubu sára rẹ̀; wọn fi dárà sí i. Gígùn aṣọ títa kọ̀ọ̀kan jẹ́ igbọnwọ mejidinlọgbọn, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹrin, gbogbo wọn rí bákan náà. Ó rán marun-un ninu àwọn aṣọ títa náà pọ̀, ó sì rán marun-un yòókù pọ̀ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Ó mú aṣọ aláwọ̀ aró, wọ́n fi rán ojóbó sára aṣọ títa tí ó kángun síta ninu àránpọ̀ aṣọ kinni, wọ́n sì tún rán ojóbó sára aṣọ títa tó kángun síta ninu àránpọ̀ aṣọ keji bákan náà. Aadọta ojóbó ni wọ́n rán mọ́ àránpọ̀ aṣọ títa kinni, aadọta ojóbó náà ni wọ́n sì rán mọ́ etí àránpọ̀ aṣọ títa keji, àwọn ojóbó náà dojú kọ ara wọn. Wọ́n ṣe aadọta ìkọ́ wúrà, wọ́n fi àwọn ìkọ́ náà kọ́ àránpọ̀ aṣọ títa náà mọ́ ara wọn, bẹ́ẹ̀ ni àgọ́ náà ṣe di odidi kan. Wọ́n tún mú aṣọ títa mọkanla tí wọ́n fi irun ewúrẹ́ ṣe, wọ́n rán an pọ̀, wọ́n fi ṣe ìbòrí sí àgọ́ náà. Gígùn aṣọ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹrin; bákan náà ni òòró ati ìbú àwọn aṣọ mọkọọkanla. Wọ́n rán marun-un pọ̀ ninu àwọn aṣọ títa náà, lẹ́yìn náà ó rán mẹfa yòókù pọ̀. Wọ́n ṣe aadọta ojóbó sára èyí tí ó kángun síta lára àránpọ̀ aṣọ kinni, ati èyí tí ó kángun síta lára àránpọ̀ aṣọ keji. Wọ́n sì ṣe aadọta ìkọ́ idẹ láti fi mú aṣọ àgọ́ náà papọ̀ kí ó lè di ẹyọ kan ṣoṣo. Wọ́n fi awọ àgbò tí wọ́n ṣe ní pupa ati awọ ewúrẹ́ ṣe ìbòrí àgọ́ náà. Lẹ́yìn náà, wọ́n fi igi akasia ṣe àkànpọ̀ igi tí ó dúró lóòró fún àgọ́ náà. Gígùn àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan jẹ́ igbọnwọ mẹ́wàá, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn àkànpọ̀ igi náà ní ìkọ́ meji meji láti fi mú wọn pọ̀ mọ́ ara wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe gbogbo àwọn àkànpọ̀ igi àgọ́ náà. Wọ́n ṣe ogún àkànpọ̀ igi fún apá gúsù àgọ́ náà, wọ́n sì ṣe ogoji ìtẹ́lẹ̀ fadaka tí wọ́n fi sí abẹ́ ogún àkànpọ̀ igi náà, ìtẹ́lẹ̀ meji meji lábẹ́ àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan fún àwọn ìkọ́ rẹ̀ mejeeji. Wọ́n ṣe ogún àkànpọ̀ igi fún ẹ̀gbẹ́ àríwá àgọ́ mímọ́ náà, pẹlu ogoji ìtẹ́lẹ̀ fadaka; ìtẹ́lẹ̀ meji meji lábẹ́ àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan. Wọ́n ṣe àkànpọ̀ igi mẹfa fún ẹ̀yìn àgọ́ náà ní apá ìwọ̀ oòrùn. Wọ́n sì ṣe àkànpọ̀ igi meji fún igun àgọ́ náà tí ó wà ní apá ẹ̀yìn. Àwọn àkànpọ̀ igi náà wà lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìsàlẹ̀, ṣugbọn wọ́n so wọ́n pọ̀ ní òkè ní ibi òrùka kinni, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe àwọn àkànpọ̀ igi kinni ati ekeji fún igun mejeeji àgọ́ náà. Àwọn àkànpọ̀ igi tí wọ́n wà ní igun kinni-keji jẹ́ mẹjọ pẹlu ìtẹ́lẹ̀ fadaka mẹrindinlogun, ìtẹ́lẹ̀ meji meji wà lábẹ́ àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan. Wọ́n fi igi akasia ṣe àwọn ọ̀pá ìdábùú mẹẹdogun, marun-un fún àwọn àkànpọ̀ igi tí wọ́n wà ní ẹ̀gbẹ́ gúsù, marun-un fún àwọn ti ẹ̀gbẹ́ àríwá, marun-un fún àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn, lápá ìwọ̀ oòrùn àgọ́ náà. Wọ́n fi ọ̀pá ìdábùú kan la àwọn àkànpọ̀ igi náà láàrin, ọ̀pá náà kan igun kinni-keji àgọ́ náà. Wọ́n yọ́ wúrà bo gbogbo àkànpọ̀ igi náà, wọ́n fi wúrà ṣe ìkọ́ fún àwọn àkànpọ̀ igi náà, wọ́n sì yọ́ wúrà bo àwọn ọ̀pá ìdábùú náà pẹlu. Aṣọ aláwọ̀ aró, ati ti elése àlùkò, ati aṣọ pupa ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ni wọ́n fi ṣe aṣọ àgọ́ náà, wọ́n sì ya àwòrán Kerubu sí i lára. Wọ́n fi igi akasia ṣe òpó mẹrin, wọ́n sì yọ́ wúrà bò ó. Wúrà ni wọ́n fi ṣe àwọn ìkọ́ wọn pẹlu, wọ́n sì fi fadaka ṣe ìtẹ́lẹ̀ mẹrin fún àwọn òpó náà. Wọ́n fi aṣọ aláwọ̀ aró, ati ti elése àlùkò, ati aṣọ pupa, ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà, wọ́n sì ṣe iṣẹ́ ọnà aláràbarà sí i lára. Òpó marun-un ni wọ́n ṣe fún àwọn aṣọ títa náà, wọ́n sì ṣe ìkọ́ sí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Wọ́n yọ́ wúrà bo àwọn òpó náà, ati àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi gbé àwọn aṣọ títa náà kọ́, ṣugbọn idẹ ni wọ́n fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ àwọn maraarun. Besaleli fi igi akasia àpótí ẹ̀rí náà, gígùn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji ààbọ̀, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀, ó sì ga ní igbọnwọ kan ààbọ̀. Ó yọ́ wúrà bò ó ninu ati lóde, ó sì tún fi wúrà ṣe ìgbátí rẹ̀. Ó da òrùka wúrà mẹrin, ó jó ọ̀kọ̀ọ̀kan mọ́ igun kọ̀ọ̀kan àpótí ẹ̀rí náà, òrùka meji lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni, meji lẹ́gbẹ̀ẹ́ keji. Ó fi igi akasia ṣe ọ̀pá, ó sì yọ́ wúrà bò wọ́n. Ó ti àwọn ọ̀pá náà bọ inú àwọn òrùka tí wọ́n wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àpótí ẹ̀rí náà láti máa fi gbé e. Ó fi ojúlówó wúrà ṣe ìtẹ́ àánú, gígùn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji ààbọ̀, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀. Ó sì fi wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ṣe àwọn Kerubu meji, ó jó wọn mọ́ igun kinni keji ìtẹ́ àánú náà, Kerubu kinni wà ní igun kinni, Kerubu keji sì wà ní igun keji. Àwọn Kerubu náà na ìyẹ́ wọn bo ìtẹ́ àánú náà; wọ́n kọjú sí ara wọn, wọ́n ń wo ìtẹ́ àánú. Ó fi igi akasia kan tabili kan; gígùn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan, gíga rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀. Ó yọ́ ojúlówó wúrà bò ó, ó sì fi wúrà ṣe ìgbátí rẹ̀. Ìgbátí tí ó ṣe náà fẹ̀ ní àtẹ́lẹwọ́ kan ati ààbọ̀. Ó da òrùka wúrà mẹrin, ó jó ọ̀kọ̀ọ̀kan mọ́ ẹsẹ̀ mẹrẹẹrin tabili náà lábẹ́ ìgbátí rẹ̀, àwọn òrùka yìí ni wọ́n máa ń ti ọ̀pá bọ̀ láti fi gbé tabili náà. Ó fi igi akasia ṣe ọ̀pá tí wọ́n fi máa ń gbé tabili náà, ó sì yọ́ wúrà bò wọ́n. Wúrà ni ó fi ṣe gbogbo àwọn ohun èlò tí yóo máa wà lórí tabili náà: àwọn àwo pẹrẹsẹ ati àwọn àwo kòtò fún turari, abọ́, ati ife tí wọn yóo máa fi ta nǹkan sílẹ̀ fún ètùtù. Ó fi ojúlówó wúrà ṣe ọ̀pá fìtílà. Wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni ó fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ ati ọ̀pá ìgbámú rẹ̀, àṣepọ̀ ni ó ṣe é, pẹlu àwọn fìtílà rẹ̀, ati àwọn kinní kan bí òdòdó tí ó fi dárà sí i lára. Ẹ̀ka mẹfa ni ó yọ lára ọ̀pá fìtílà náà; mẹta lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni, mẹta lẹ́gbẹ̀ẹ́ keji. Ó ṣe àwọn kinní kan bí òdòdó alimọndi mẹta mẹta sórí ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀ka mẹfẹẹfa tí ó yọ lára ọ̀pá fìtílà náà. Ife mẹrin ni ó ṣe sórí ọ̀pá fìtílà náà gan-an, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dàbí òdòdó alimọndi pẹlu ìrudi ati ìtànná rẹ̀. Ìrudi kọ̀ọ̀kan wà lábẹ́ ẹ̀ka meji meji tí ó so mọ́ ara ọ̀pá fìtílà náà lọ́nà mẹtẹẹta. Àṣepọ̀ ni ó ṣe ọ̀pá fìtílà ati ẹ̀ka ara rẹ̀ ati ìrudi abẹ́ wọn; ojúlówó wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni ó fi ṣe wọ́n. Fìtílà meje ni ó ṣe fún ọ̀pá náà, ojúlówó wúrà ni ó fi ṣe ọ̀pá tí a fi ń pa iná ẹnu fìtílà. Odidi talẹnti wúrà marundinlaadọrin ni ó lò lórí ọ̀pá fìtílà yìí ati àwọn ohun èlò tí wọ́n jẹ mọ́ ti ọ̀pá fìtílà. Ó fi igi akasia ṣe pẹpẹ turari kan, bákan náà ni gígùn ati fífẹ̀ rẹ̀ rí, wọ́n jẹ́ igbọnwọ kọ̀ọ̀kan, gíga rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ meji. Àṣepọ̀ ni wọ́n ṣe é pẹlu ìwo rẹ̀ mẹrẹẹrin. Ó yọ́ ojúlówó wúrà bò ó, ati òkè ati ẹ̀gbẹ́ ati abẹ́ rẹ̀, ati ìwo rẹ̀ pẹlu, ó sì fi wúrà ṣe ìgbátí rẹ̀. Ó da òrùka wúrà meji meji, ó jó wọn mọ́ abẹ́ ìgbátí pẹpẹ náà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni-keji, òrùka wọnyi ni wọn yóo máa ti ọ̀pá bọ̀ láti fi gbé pẹpẹ náà. Ó fi igi akasia ṣe àwọn ọ̀pá rẹ̀, ó sì yọ́ wúrà bò wọ́n. Ó ṣe òróró ìyàsímímọ́ ati turari olóòórùn dídùn bí àwọn tí wọn ń ṣe turari ṣe máa ń ṣe é. Ó fi igi akasia ṣe pẹpẹ ẹbọ sísun, bákan náà ni gígùn ati fífẹ̀ pẹpẹ náà rí, wọ́n jẹ́ igbọnwọ marun-un marun-un, gíga rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹta. Ó ṣe ìwo kọ̀ọ̀kan sí igun mẹrẹẹrin pẹpẹ náà, àṣepọ̀ mọ́ pẹpẹ ni ó ṣe àwọn ìwo náà, ó sì yọ́ idẹ bò wọ́n. Ó fi idẹ ṣe gbogbo àwọn ohun èlò tí ó jẹ mọ́ ti pẹpẹ náà: àwọn bíi ìkòkò, ọ̀kọ̀, agbada, ọ̀kọ̀ tí wọ́n fi ń mú ẹran ati àwo ìfọnná; idẹ ni ó fi ṣe gbogbo wọn. Ó fi idẹ ṣe ayanran ààrò kan fún pẹpẹ náà, ó ṣe é mọ́ abẹ́ ìgbátí rẹ̀, ayanran náà sì bò ó dé agbede meji sí ìsàlẹ̀. Ó da òrùka mẹrin, ó jó ọ̀kọ̀ọ̀kan mọ́ igun kọ̀ọ̀kan ayanran idẹ náà, àwọn òrùka wọnyi ni wọ́n máa ń ti ọ̀pá bọ̀ láti fi gbé pẹpẹ náà. Ó fi igi akasia ṣe àwọn ọ̀pá, ó sì yọ́ idẹ bò wọ́n. Ó ti àwọn ọ̀pá náà bọ àwọn òrùka tí wọ́n wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji pẹpẹ náà láti máa fi gbé e; pákó ni ó fi ṣe àwọn ọ̀pá náà, wọ́n sì ní ihò ninu. Ó mu dígí onídẹ, tí àwọn obinrin tí ń ṣiṣẹ́ ìsìn lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ ń lò, ó fi ṣe agbada idẹ kan, ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Ó ṣe àgbàlá kan, aṣọ funfun, onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, ni ó fi ṣe aṣọ títa ìhà gúsù àgbàlá náà, gígùn rẹ̀ jẹ́ ọgọrun-un igbọnwọ. Ogún ni àwọn òpó aṣọ títa, àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn náà sì jẹ́ ogún. Idẹ ni ó fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ wọn, ṣugbọn fadaka ni ó fi ṣe ìkọ́ ati àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ wọn. Gígùn apá àríwá àgọ́ náà jẹ́ ọgọrun-un igbọnwọ pẹlu, ogún ni àwọn òpó rẹ̀, àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn sì jẹ́ ogún pẹlu. Idẹ ni wọ́n fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ wọn, ṣugbọn fadaka ni wọ́n fi ṣe ìkọ́ ati àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ wọn. Gígùn aṣọ títa fún apá ìwọ̀ oòrùn jẹ́ aadọta igbọnwọ, òpó rẹ̀ jẹ́ mẹ́wàá, àwọn àtẹ̀bọ̀ rẹ̀ náà jẹ́ mẹ́wàá; fadaka ni wọ́n fi ṣe àwọn ìkọ́ ati àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ wọn. Aṣọ títa ti iwájú àgọ́ náà, ní apá ìlà oòrùn gùn ní ìwọ̀n aadọta igbọnwọ. Aṣọ títa fún apá kan ẹnu ọ̀nà jẹ́ igbọnwọ mẹẹdogun, ó ní òpó mẹta ati ìtẹ́lẹ̀ mẹta. Bákan náà ni aṣọ títa ẹ̀gbẹ́ kinni keji ẹnu ọ̀nà náà rí, wọ́n gùn ní ìwọ̀n igbọnwọ mẹẹdogun mẹẹdogun, wọ́n ní òpó mẹta mẹta ati ìtẹ́lẹ̀ mẹta mẹta. Aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ni wọ́n fi ṣe gbogbo aṣọ títa tí ó wà ninu àgbàlá náà. Idẹ ni wọ́n fi ṣe gbogbo àwọn ìtẹ́lẹ̀ òpó rẹ̀; ṣugbọn fadaka ni wọ́n fi ṣe àwọn ìkọ́ ati àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ wọn, fadaka ni wọ́n yọ́ bo àwọn ìbòrí wọn, fadaka ni wọ́n sì fi bo gbogbo àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ fún aṣọ títa wọn. Wọ́n fi abẹ́rẹ́ ṣe iṣẹ́ ọnà sára aṣọ títa ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà, pẹlu aṣọ aláwọ̀ aró, ati aṣọ elése àlùkò, ati aṣọ pupa, ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, ó gùn ní ogún igbọnwọ, ó sì ga ní igbọnwọ marun-un gẹ́gẹ́ bí àwọn aṣọ títa ti àgbàlá náà. Òpó mẹrin ni aṣọ títa tí ẹnu ọ̀nà yìí ní, pẹlu ìtẹ́lẹ̀ idẹ mẹrin. Fadaka ni wọ́n fi ṣe àwọn ìkọ́ ati àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, fadaka ni wọ́n sì fi bo àwọn ìbòrí òpó náà. Idẹ ni wọ́n fi ṣe gbogbo àwọn èèkàn àgọ́ náà, ati ti gbogbo àgbàlá rẹ̀. Ìṣirò ohun tí wọ́n lò fún kíkọ́ àgọ́ ẹ̀rí wíwà OLUWA nìyí: Mose ni ó pàṣẹ pé kí ọmọ Lefi ṣe ìṣirò àwọn ohun tí wọ́n lò lábẹ́ àkóso Itamari ọmọ Aaroni, alufaa. Besaleli ọmọ Uri, ọmọ ọmọ Huri, ti ẹ̀yà Juda ṣe gbogbo ohun tí Ọlọrun pa láṣẹ fún Mose. Oholiabu, ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀yà Dani, wà pẹlu rẹ̀. Oholiabu yìí mọ iṣẹ́ ọnà gan-an. Bákan náà, ó lè lo aṣọ aláwọ̀ aró ati elése àlùkò, ati aṣọ pupa ati aṣọ onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ láti ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà. Gbogbo wúrà tí wọ́n lò fún kíkọ́ àgọ́ náà jẹ́ ìwọ̀n talẹnti mọkandinlọgbọn ati ẹẹdẹgbẹrin ìwọ̀n ṣekeli ó lé ọgbọ̀n (730), ìwọ̀n tí wọn ń lò ninu àgọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Fadaka tí àwọn tí wọ́n kà ninu àwọn eniyan náà dájọ jẹ́ ọgọrun-un ìwọ̀n talẹnti, ati ẹẹdẹgbẹsan ìwọ̀n ṣekeli ó lé marundinlọgọrin (1,775), ìwọ̀n tí wọ́n máa ń lò ninu àgọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwọn tí wọ́n kà ninu àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n dá wúrà ati fadaka ati idẹ yìí jọ. Olukuluku àwọn tí wọ́n tó ọmọ ogún ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí wọ́n kà dá ìdajì ìwọ̀n ṣekeli kọ̀ọ̀kan tí òfin wí, ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ilé OLUWA ni wọ́n sì fi wọ̀n ọ́n, iye àwọn eniyan tí wọ́n kà jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́, ati ẹgbẹtadinlogun ó lé aadọjọ (603,550). Ọgọrun-un talẹnti fadaka yìí ni wọ́n fi ṣe àwọn ìtẹ́lẹ̀ òpó ilé OLUWA ati ìtẹ́lẹ̀ àwọn aṣọ títa. Ọgọrun-un talẹnti ni wọ́n lò láti ṣe ọgọrun-un ìtẹ́lẹ̀, talẹnti kọ̀ọ̀kan fún ìtẹ́lẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Ninu ẹẹdẹgbẹsan ó lé marundinlọgọrin (1,775) ìwọ̀n ṣekeli fadaka ni ó ti ṣe àwọn ìkọ́ fún àwọn òpó náà, ara rẹ̀ ni ó yọ́ lé àwọn ìbòrí wọn, tí ó sì tún fi ṣe àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ fún aṣọ títa wọn. Àwọn idẹ tí wọ́n dájọ jẹ́ aadọrin ìwọ̀n talẹnti ati ẹgbaa ó lé irinwo (2,400) ìwọ̀n ṣekeli. Idẹ yìí ni ó lò láti ṣe ìtẹ́lẹ̀ àwọn ìlẹ̀kùn àgọ́ àjọ, ati pẹpẹ onídẹ, ati àwọn idẹ inú rẹ̀ ati gbogbo àwọn ohun èlò ibi pẹpẹ náà. Lára rẹ̀ ni wọ́n ti ṣe ìtẹ́lẹ̀ àwọn òpó àgọ́ náà yípo ati àwọn èèkàn àgọ́ ati àwọn èèkàn àgbàlá inú rẹ̀. Wọ́n fi aṣọ aláwọ̀ aró, ati ti elése àlùkò, ati aṣọ pupa, rán ẹ̀wù aláràbarà tí àwọn alufaa yóo máa wọ̀ ninu ibi mímọ́ náà fún Aaroni gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. Ó fi wúrà, aṣọ aláwọ̀ aró, ti elése àlùkò ati aṣọ pupa ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ rán efodu. Ó fi òòlù lu wúrà, ó sì gé e tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ bí okùn, wọ́n fi ṣe iṣẹ́ ọnà sára aṣọ aláwọ̀ aró ati ti elése àlùkò ati aṣọ pupa ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́. Wọ́n ṣe aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ meji fún èjìká efodu náà, wọ́n rán wọn mọ́ ẹ̀gbẹ́ kinni keji rẹ̀ láti máa fi so wọ́n mọ́ ara wọn. Wọ́n fi irú aṣọ kan náà ṣe àmùrè dáradára kan. Àṣepọ̀ ni wọ́n ṣe é mọ́ efodu yìí láti máa fi so ó gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. Wọ́n tọ́jú àwọn òkúta onikisi, wọ́n jó wọn mọ́ ojú ìtẹ́lẹ̀ wúrà, wọ́n kọ orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli sí ara wọn, bí wọ́n ti máa ń kọ orúkọ sí ara òrùka èdìdì. Ó tò wọ́n sí ara èjìká efodu náà gẹ́gẹ́ bí òkúta ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli, bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. Irú aṣọ tí wọ́n fi ṣe efodu náà ni wọ́n fi ṣe ìgbàyà rẹ̀, wọ́n fi wúrà, aṣọ aláwọ̀ aró, ti elése àlùkò, aṣọ pupa ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe iṣẹ́ ọnà sí i lára. Bákan náà ni òòró ati ìbú aṣọ ìgbàyà náà, ìṣẹ́po aṣọ meji ni wọ́n sì rán pọ̀. Ìká kan ni òòró rẹ̀, ìká kan náà sì ni ìbú rẹ̀. Wọ́n to òkúta olówó iyebíye sí i lára ní ẹsẹ̀ mẹrin, wọ́n to òkúta sadiu ati topasi ati kabọnku sí ẹsẹ̀ kinni, wọ́n to emeradi ati safire ati dayamọndi sí ẹsẹ̀ keji, wọ́n to jasiniti, agate ati ametisti sí ẹsẹ̀ kẹta; wọ́n to bẹrili ati onikisi ati Jasperi sí ẹsẹ̀ kẹrin, wọ́n sì fi ìtẹ́lẹ̀ wúrà jó wọn mọ́ ìgbàyà náà. Oríṣìí òkúta mejila ni ó wà níbẹ̀; orúkọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dúró fún orúkọ ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli kọ̀ọ̀kan, wọ́n dàbí èdìdì, wọn sì kọ orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli mejeejila sí wọn lára, òkúta kan fún ẹ̀yà kan. Wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe ẹ̀wọ̀n tí a lọ́pọ̀ gẹ́gẹ́ bí okùn fún ìgbàyà náà. Wọ́n ṣe ojú ìdè wúrà meji, ati òrùka wúrà meji, wọ́n fi òrùka wúrà mejeeji sí etí kinni keji ìgbàyà náà. Wọ́n ti àwọn ẹ̀wọ̀n wúrà mejeeji náà bọ àwọn òrùka mejeeji tí wọ́n wà ní etí kinni keji ìgbàyà náà. Wọ́n mú etí kinni keji ẹ̀wọ̀n wúrà mejeeji, wọ́n so wọ́n mọ́ ojú ìdè wúrà ara ìgbàyà náà, wọ́n sì so wọ́n mọ́ èjìká efodu náà. Lẹ́yìn náà wọ́n da òrùka wúrà meji, wọ́n sì dè wọ́n mọ́ etí kinni keji ìgbàyà náà, lọ́wọ́ inú ní ẹ̀gbẹ́ tí ó kan ara efodu. Wọ́n sì da òrùka wúrà meji mìíràn, wọ́n dè wọ́n mọ́ ìsàlẹ̀ èjìká efodu náà níwájú, lókè ibi tí ó ti so pọ̀ mọ́ àmùrè rẹ̀. Òrùka aṣọ ìgbàyà yìí ni wọ́n fi dè é mọ́ òrùka ara efodu pẹlu aṣọ aláwọ̀ aró tẹ́ẹ́rẹ́ kan, kí ó lè sùn lé àmùrè efodu náà tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára, kí ìgbàyà náà má baà tú kúrò lára efodu, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. Ó fi aṣọ aláwọ̀ aró rán ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ sí efodu náà, wọ́n yọ ọrùn sí ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ náà bí ọrùn ẹ̀wù gan-an, wọ́n sì fi aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́ gbá a yípo kí ó má baà ya. Wọ́n fi aṣọ aláwọ̀ aró, ti elése àlùkò, ati aṣọ pupa ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe àwòrán èso Pomegiranate sí etí ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ náà nísàlẹ̀. Wọ́n sì fi agogo ojúlówó wúrà kéékèèké la àwọn àwòrán èso Pomegiranate náà láàrin. Agogo wúrà kan, àwòrán èso Pomegiranate kan, agogo wúrà kan, àwòrán èso Pomegiranate kan, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tò wọ́n yípo etí ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ náà, fún ṣíṣe iṣẹ́ alufaa gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. Wọ́n fi aṣọ funfun dáradára dá ẹ̀wù meji fún Aaroni ati fún àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n fi ṣe adé, ati fìlà ati ṣòkòtò. Wọ́n fi aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, ti aláwọ̀ aró, ti elése àlùkò ati aṣọ pupa tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára ṣe àmùrè gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. Wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe ìgbátí adé mímọ́ náà, wọ́n sì kọ àkọlé kan sí ara rẹ̀ bí wọ́n ti ń kọ ọ́ sí ara òrùka èdìdì, pé, “Mímọ́ fún OLUWA.” Wọ́n so aṣọ aláwọ̀ aró tẹ́ẹ́rẹ́ kan mọ́ ọn, láti máa fi so ó mọ́ etí adé náà gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo iṣẹ́ àgọ́ àjọ náà ṣe parí, àwọn ọmọ Israẹli ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. Wọ́n sì gbé àgọ́ àjọ náà tọ Mose wá, àgọ́ náà ati gbogbo àwọn ohun èlò inú rẹ̀, àwọn ìkọ́ rẹ̀, àwọn àkànpọ̀ igi inú rẹ̀, àwọn igi ìdábùú inú rẹ̀, àwọn òpó rẹ̀, ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn; ìbòrí tí wọ́n fi awọ ewúrẹ́ ati awọ àgbò ṣe tí wọ́n kùn láwọ̀ pupa, ati aṣọ ìbòjú inú àgọ́ náà. Bẹ́ẹ̀ náà ni àpótí ẹ̀rí pẹlu àwọn òpó rẹ̀ ati ìtẹ́ àánú náà; ati tabili náà, pẹlu gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀ ati burẹdi ìfihàn. Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá fìtílà tí a fi ojúlówó wúrà ṣe, ati àwọn fìtílà orí rẹ̀, pẹlu gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, ati òróró ìtànná rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni pẹpẹ wúrà náà, ati òróró ìyàsímímọ́, ati turari olóòórùn dídùn, ati aṣọ títa fún ìlẹ̀kùn àgọ́ mímọ́ náà; ati pẹpẹ idẹ ati ààrò idẹ rẹ̀, àwọn ọ̀pá rẹ̀ ati gbogbo ohun èlò rẹ̀, agbada idẹ ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni aṣọ títa ti àgbàlá náà, àwọn òpó rẹ̀ ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn, ati aṣọ fún ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà, okùn rẹ̀ ati àwọn èèkàn rẹ̀, ati gbogbo ohun èlò fún ìsìn ninu àgọ́ mímọ́ náà, ati fún àgọ́ àjọ náà. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ẹ̀wù tí a ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà sí fún iṣẹ́ ìsìn àwọn alufaa ninu ibi mímọ́, ẹ̀wù mímọ́ fún Aaroni alufaa ati ẹ̀wù fún àwọn ọmọ rẹ̀ náà, tí wọn yóo fi máa ṣe iṣẹ́ wọn bí alufaa. Gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose, ni àwọn eniyan Israẹli ṣe gbogbo iṣẹ́ náà. Mose wo gbogbo iṣẹ́ náà, ó rí i pé wọ́n ṣe é gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ, Mose sì súre fún wọn. OLUWA sọ fún Mose pé, “Kọ́ àgọ́ ìpàdé ní ọjọ́ kinni oṣù kinni. Kí o sì gbé àpótí ẹ̀rí tí òfin mẹ́wàá wà ninu rẹ̀ sinu àgọ́ náà, kí o sì ta aṣọ ìbòjú dí i. Lẹ́yìn náà, gbé tabili náà wọ inú rẹ̀, pẹlu àwọn nǹkan tí wọn yóo máa lò pẹlu rẹ̀, kí o sì tò wọ́n sí ààyè wọn. Lẹ́yìn náà, gbé ọ̀pá fìtílà náà wọ inú rẹ̀, kí o sì to àwọn fìtílà orí rẹ̀ sí ààyè wọn. Lẹ́yìn náà, gbé pẹpẹ wúrà turari siwaju àpótí ẹ̀rí náà, kí o sì ta aṣọ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà. Gbé pẹpẹ ẹbọ sísun kalẹ̀ níwájú ẹnu ọ̀nà àgọ́ mímọ́ ti àgọ́ àjọ náà. Gbé agbada omi náà sí ààrin, ní agbede meji àgọ́ àjọ ati pẹpẹ náà, kí o sì pọn omi sinu rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ṣe àgbàlá yí i ká, kí o sì ta aṣọ sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà. “Lẹ́yìn náà, mú òróró ìyàsímímọ́, kí o ta á sí ara àgọ́ náà, ati sí ara ohun gbogbo tí ó wà ninu rẹ̀, kí o yà á sí mímọ́ pẹlu gbogbo àwọn ohun èlò inú rẹ̀, wọn yóo sì di mímọ́. Ta òróró sí ara pẹpẹ ẹbọ sísun pẹlu, ati sí ara gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, kí o ya pẹpẹ náà sí mímọ́, pẹpẹ náà yóo sì di ohun mímọ́ jùlọ. Ta òróró sí ara agbada náà pẹlu ati gbogbo ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀, kí o sì yà á sí mímọ́. “Lẹ́yìn náà, mú Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ, kí o sì fi omi wẹ̀ wọ́n. Kó àwọn ẹ̀wù mímọ́ náà wọ Aaroni, ta òróró sí i lórí, kí o sì yà á sí mímọ́ kí ó lè máa ṣe alufaa mi. Kó àwọn ọmọ rẹ̀ wá pẹlu, kí o sì wọ̀ wọ́n ní ẹ̀wù. Ta òróró sí wọn lórí, gẹ́gẹ́ bí o ti ta á sí baba wọn lórí, kí àwọn náà lè máa ṣe alufaa mi. Òróró tí o bá ta sí wọn lórí ni yóo sọ àwọn ati gbogbo ìran wọn di alufaa títí lae.” Mose ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún un patapata. Ní ọjọ́ kinni oṣù kinni ọdún keji ni wọ́n pa àgọ́ náà. Mose pa àgọ́ mímọ́ náà, ó to àwọn ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀, ó gbé àwọn àkànpọ̀ igi rẹ̀ lé wọn, ó fi àwọn igi ìdábùú àgọ́ náà dábùú àwọn àkànpọ̀ igi rẹ̀; lẹ́yìn náà, ó gbé àwọn òpó rẹ̀ nàró. Lẹ́yìn náà, ó ta aṣọ àgọ́ náà bò ó, ó sì fi ìbòrí rẹ̀ bò ó gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un. Ó kó àwọn tabili òkúta mejeeji sinu àpótí ẹ̀rí náà, ó ti àwọn ọ̀pá àpótí náà bọ inú àwọn òrùka rẹ̀, ó sì fi ìdérí rẹ̀ dé e lórí. Ó gbé àpótí ẹ̀rí náà sinu àgọ́ náà, ó sì ta aṣọ ìbòjú rẹ̀ dí i gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un. Ó gbé tabili náà sí inú àgọ́, ní apá ìhà àríwá àgọ́ mímọ́, níwájú aṣọ ìbòjú, ó sì to àwọn burẹdi náà létòlétò sórí rẹ̀ níwájú OLUWA, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un. Ó gbé ọ̀pá fìtílà náà sinu àgọ́ àjọ níwájú tabili ní apá ìhà gúsù àgọ́ náà. Ó to àwọn fìtílà rẹ̀ sórí rẹ̀ níwájú OLUWA gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un. Ó gbé pẹpẹ wúrà náà kalẹ̀ ninu àgọ́ àjọ níwájú aṣọ ìbòjú náà, ó sì sun turari olóòórùn dídùn lórí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un. Ó ta àwọn aṣọ títa ti ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà sí ààyè wọn. Ó gbé pẹpẹ ẹbọ sísun kalẹ̀ níbi ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà, ó sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un. Ó gbé agbada omi náà kalẹ̀ ní agbede meji àgọ́ àjọ ati pẹpẹ ẹbọ sísun, ó sì pọn omi sinu rẹ̀. Omi yìí ni Mose, ati Aaroni ati àwọn ọmọ Aaroni fi ń fọ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn, nígbà tí wọ́n bá ń wọ inú àgọ́ àjọ lọ, ati ìgbà tí wọ́n bá fẹ́ súnmọ́ ìdí pẹpẹ, wọn á fọ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ. Ó ṣe àgbàlá kan yí àgọ́ ati pẹpẹ náà ká, ó ta aṣọ sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà. Bẹ́ẹ̀ ni Mose ṣe parí gbogbo iṣẹ́ náà. Nígbà náà ni ìkùukùu bo àgọ́ àjọ náà, ògo OLUWA sì kún inú rẹ̀. Mose kò sì lè wọ inú rẹ̀ nítorí ìkùukùu tí ó wà lórí rẹ̀, ati pé ògo OLUWA kún inú rẹ̀. Ninu gbogbo ìrìn àjò wọn, nígbà tí ìkùukùu yìí bá gbéra kúrò lórí àgọ́ náà, àwọn ọmọ Israẹli á gbéra, wọ́n á sì tẹ̀síwájú. Ṣugbọn bí ìkùukùu yìí kò bá tíì gbéra, àwọn náà kò ní tíì tẹ̀síwájú títí tí yóo fi gbéra. Nítorí pé ninu gbogbo ìrìn àjò wọn, ìkùukùu OLUWA wà lórí àgọ́ náà lọ́sàn-án, iná sì máa ń jó ninu rẹ̀ lóru ní ìṣojú gbogbo àwọn eniyan Israẹli. OLUWA pe Mose, ó sì bá a sọ̀rọ̀ láti inú Àgọ́ Àjọ ó ní, “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, nígbà tí ẹnikẹ́ni ninu yín bá fẹ́ mú ọrẹ ẹbọ wá fún èmi OLUWA, ninu agbo mààlúù, tabi agbo ewúrẹ́, tabi agbo aguntan rẹ̀ ni kí ó ti mú un. “Bí ó bá jẹ́ pé láti inú agbo mààlúù ni ó ti mú un láti fi rú ẹbọ sísun, akọ mààlúù tí kò ní àbààwọ́n ni kí ó mú wá, kí ó mú un wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ láti fi rúbọ, kí ó lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níwájú OLUWA. Kí ó gbé ọwọ́ lé orí ẹbọ sísun náà, OLUWA yóo sì gbà á gẹ́gẹ́ bí ẹbọ láti kó ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ lọ. Kí ó pa akọ mààlúù náà níbẹ̀, kí àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá siwaju OLUWA, kí wọn da ẹ̀jẹ̀ náà yíká ara pẹpẹ tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. Mú ẹran náà, kí o bó awọ rẹ̀, kí o sì gé e sí wẹ́wẹ́; kí àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, to igi sórí pẹpẹ náà kí wọ́n sì dáná sí i. Lẹ́yìn náà, kí àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, to àwọn igẹ̀ ẹran náà ati orí rẹ̀ ati ọ̀rá rẹ̀ sórí igi tí wọ́n dáná sí, lórí pẹpẹ náà. Ṣugbọn ẹni tí ó wá rúbọ yóo fi omi fọ àwọn nǹkan inú ẹran náà ati ẹsẹ̀ rẹ̀, alufaa yóo sì sun gbogbo rẹ̀ níná lórí pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun, ẹbọ tí a fi iná sun, tí ó jẹ́ ẹbọ olóòórùn dídùn sí OLUWA. “Bí ó bá jẹ́ pé láti inú agbo aguntan tabi agbo ewúrẹ́ ni ó ti mú ẹran fún ẹbọ sísun rẹ̀, akọ tí kò ní àbààwọ́n ni kí ó mú. Kí ó pa á ní apá ìhà àríwá pẹpẹ níwájú OLUWA, kí àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí ara pẹpẹ náà yíká. Kí ó gé e sí wẹ́wẹ́, ati orí rẹ̀, ati ọ̀rá rẹ̀, kí alufaa to gbogbo rẹ̀ sórí igi tí ó wà ninu iná lórí pẹpẹ. Ṣugbọn kí ó fi omi fọ nǹkan inú rẹ̀ ati ẹsẹ̀ rẹ̀, kí alufaa fi gbogbo rẹ̀ rúbọ, kí ó sì sun ún lórí pẹpẹ náà. Ẹbọ sísun ni; ẹbọ tí a fi iná sun, tí ó ní òórùn dídùn, tí inú OLUWA dùn sí. “Bí ó bá jẹ́ pé ẹyẹ ni eniyan bá fẹ́ fi rú ẹbọ sísun, kí ó mú àdàbà tabi ọmọ ẹyẹlé wá. Alufaa yóo gbà á, yóo fa ọrùn rẹ̀ tu, yóo sì sun ún lórí pẹpẹ, lẹ́yìn tí ó bá ti ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí ara pẹpẹ tán; kí ó fa àjẹsí rẹ̀ yọ, kí ó sì tu ìyẹ́ rẹ̀, kí ó dà á sí apá ìhà ìlà oòrùn pẹpẹ náà, níbi tí wọn ń da eérú sí. Kí ó fa apá rẹ̀ mejeeji ya, ṣugbọn kí ó má fà wọ́n já. Lẹ́yìn náà kí alufaa sun ún lórí igi tí ó wà ninu iná lórí pẹpẹ. Ẹbọ sísun ni, ẹbọ olóòórùn dídùn tí a fi iná sun sí OLUWA. “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ mú ọkà wá siwaju OLUWA láti fi rúbọ, ó gbọdọ̀ jẹ́ ìyẹ̀fun dáradára, kí ó da òróró ati turari sórí rẹ̀. Kí ó gbé e tọ àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, lọ, kí alufaa náà bu ẹ̀kúnwọ́ kan ninu ìyẹ̀fun náà, pẹlu òróró ati turari tí ó wà lórí rẹ̀. Ẹ̀kúnwọ́ kan yìí ni alufaa yóo sun fún ìrántí, ẹbọ olóòórùn dídùn, tí a fi iná sun sí OLUWA. Ohun tí ó ṣẹ́kù ninu ìyẹ̀fun náà di ti Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀. Òun ló mọ́ jùlọ, nítorí pé apá kan ninu ẹbọ sísun sí OLUWA ni. “Bí ó bá jẹ́ pé ohun jíjẹ tí a yan lórí ààrò ni ẹbọ náà, kò gbọdọ̀ sí ìwúkàrà ninu rẹ̀. Ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára tí a fi òróró pò ni wọ́n gbọdọ̀ fi yan án, ó sì lè jẹ́ burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí kò ní ìwúkàrà ninu tí a da òróró lé lórí. “Bí ó bá jẹ́ pé ohun jíjẹ tí a yan lórí ààrò ni ó fi rúbọ, kí ó jẹ́ èyí tí ìyẹ̀fun rẹ̀ kúnná dáradára, tí a fi òróró pò, kí ó má sì ní ìwúkàrà ninu. Já a sí wẹ́wẹ́, kí o sì da òróró lé e lórí, ẹbọ ohun jíjẹ ni. “Bí ẹbọ rẹ bá jẹ́ ti ohun jíjẹ tí a sè ninu ìkòkò, ìyẹ̀fun rẹ̀ gbọdọ̀ kúnná dáradára kí ó sì ní òróró. Gbé àwọn ẹbọ ohun jíjẹ náà wá siwaju OLUWA. Nígbà tí o bá gbé e fún alufaa, yóo gbé e wá síbi pẹpẹ. Alufaa yóo wá bu díẹ̀ ninu ẹbọ ohun jíjẹ yìí, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí, yóo sì sun ún lórí pẹpẹ. Ẹbọ tí a fi iná sun ni, tí ó ní òórùn dídùn tí inú OLUWA sì dùn sí. Ohun tí ó bá ṣẹ́kù ninu ohun jíjẹ náà di ti Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀. Òun ni ó mọ́ jùlọ lára ẹbọ tí a fi iná sun sí OLUWA. “Ẹbọ ohun jíjẹ tí o bá mú wá fún OLUWA kò gbọdọ̀ ní ìwúkàrà ninu, nítorí pé ìwúkàrà tabi oyin kò gbọdọ̀ sí ninu ẹbọ sísun sí OLUWA. O lè mú wọn wá fún OLUWA gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àkọ́so oko, ṣugbọn wọn kò gbọdọ̀ fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ bí ẹbọ olóòórùn dídùn. Gbogbo ẹbọ ohun jíjẹ rẹ ni o gbọdọ̀ fi iyọ̀ sí, o kò gbọdọ̀ jẹ́ kí iyọ̀ wọ́n ninu ọrẹ ohun jíjẹ rẹ; nítorí pé iyọ̀ ni ẹ̀rí majẹmu láàrin ìwọ pẹlu Ọlọrun rẹ, o níláti máa fi iyọ̀ sí gbogbo ẹbọ rẹ. Bí o bá fẹ́ fi àkọ́so oko rẹ rú ẹbọ ohun jíjẹ sí OLUWA, ninu ṣiiri ọkà àkọ́so oko rẹ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ pa ni kí o ti mú, kí o yan án lórí iná. Da òróró sí i, kí o sì fi turari sórí rẹ̀. Ẹbọ ohun jíjẹ ni. Alufaa yóo bù ninu ọkà pípa ati òróró náà, pẹlu gbogbo turari orí rẹ̀, yóo sun ún gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fún ìrántí. Ẹbọ sísun sí OLUWA ni. “Bí ẹnìkan bá fẹ́ rú ẹbọ alaafia, tí ó sì mú ẹran láti inú agbo ẹran rẹ̀ fún ẹbọ náà, kì báà jẹ́ akọ tabi abo, ó níláti jẹ́ èyí tí kò ní àbààwọ́n níwájú OLUWA. Kí ó gbé ọwọ́ lé orí ẹran náà, kí ó sì pa á lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. Kí àwọn alufaa ọmọ Aaroni da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sára pẹpẹ náà yípo. Kí ó mú àwọn nǹkan wọnyi ninu ẹbọ alaafia náà, kí ó fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí OLUWA: ọ̀rá tí ó bo nǹkan inú rẹ̀ ati ọ̀rá tí ó wà lára ìfun rẹ̀, ati kíndìnrín rẹ̀ mejeeji pẹlu ọ̀rá tí ó bò wọ́n. Nígbà tí ó bá ń yọ kíndìnrín rẹ̀, yóo yọ ẹ̀dọ̀ rẹ̀ mọ́ ọn láti fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA. Àwọn ọmọ Aaroni yóo sun wọ́n lórí igi tí ó wà ninu iná lórí pẹpẹ; ẹbọ sísun ni, tí ó ní òórùn dídùn, tí inú OLUWA sì dùn sí. “Bí ó bá jẹ́ pé aguntan tabi ewúrẹ́ ni yóo mú láti inú agbo ẹran rẹ̀ láti fi rú ẹbọ alaafia sí OLUWA, kì báà jẹ́ akọ tabi abo ẹran, ó gbọdọ̀ jẹ́ èyí tí kò ní àbààwọ́n. Bí ó bá jẹ́ ọ̀dọ́ aguntan ni yóo fi rúbọ, kí ó mú un wá siwaju OLUWA, kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, kí ó sì pa á níwájú Àgọ́ Àjọ náà; kí àwọn ọmọ Aaroni da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí ara pẹpẹ náà yípo. Kí ó mú àwọn nǹkan wọnyi ninu ẹbọ alaafia náà, kí ó fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí OLUWA: ọ̀rá rẹ̀, gbogbo ọ̀rá tí ó wà ní ìrù rẹ̀ títí dé ibi egungun ẹ̀yìn rẹ̀, ati gbogbo ọ̀rá tí ó bo gbogbo nǹkan inú rẹ̀ ati ọ̀rá tí ó wà lára ìfun rẹ̀, kíndìnrín rẹ̀ mejeeji, ati ọ̀rá tí ó bò wọ́n níbi ìbàdí ati gbogbo ẹ̀dọ̀ rẹ̀. Alufaa yóo sì sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ tí a fi iná sun sí OLUWA. “Bí ó bá jẹ́ pé ewúrẹ́ ni yóo fi rú ẹbọ náà, kí ó mú un wá siwaju OLUWA, kí ó gbé ọwọ́ lé e lórí, kí ó sì pa á níwájú Àgọ́ Àjọ náà; àwọn ọmọ Aaroni yóo sì da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sára pẹpẹ náà yípo. Yóo sì yọ àwọn nǹkan wọnyi ninu rẹ̀ láti fi rú ẹbọ tí a fi iná sun sí OLUWA: gbogbo ọ̀rá tí ó bo àwọn nǹkan inú rẹ̀, ati ọ̀rá tí ó bo ìfun rẹ̀, kíndìnrín rẹ̀ mejeeji, pẹlu ọ̀rá tí ó bò wọ́n níbi ìbàdí, ati ẹ̀dọ̀ rẹ̀. Kí alufaa sun wọ́n lórí pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun olóòórùn dídùn. Ti OLUWA ni gbogbo ọ̀rá ẹran. Kí èyí jẹ́ ìlànà ayérayé fún àtìrandíran yín, ní gbogbo ibùgbé yín, pé ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ọ̀rá tabi ẹ̀jẹ̀.” OLUWA ní kí Mose sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, bí ẹnikẹ́ni bá ṣèèṣì ṣe ọ̀kankan ninu ohun tí OLUWA pa láṣẹ pé wọn kò gbọdọ̀ ṣe, ohun tí wọn óo ṣe nìyí: “Bí ó bá jẹ́ alufaa tí a fi àmì òróró yàn ni ó ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀, tí ó sì kó ẹ̀bi bá àwọn eniyan, kí ó fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ níwájú OLUWA, fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá. Yóo mú akọ mààlúù náà wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ níwájú OLUWA, yóo gbé ọwọ́ lé e lórí, yóo sì pa á níwájú OLUWA. Alufaa náà yóo wá gbà ninu ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù náà, yóo gbé e wá sinu Àgọ́ Àjọ. Yóo ti ìka rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, yóo sì wọ́n ọn sílẹ̀ nígbà meje níwájú OLUWA, níwájú aṣọ ìkélé tí ó wà ní ibi mímọ́. Lára ẹ̀jẹ̀ tí ó kù, yóo fi sára àwọn ìwo pẹpẹ turari olóòórùn dídùn tí ó wà níwájú OLUWA, ninu Àgọ́ Àjọ. Yóo sì da ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù yòókù sílẹ̀ nídìí pẹpẹ ẹbọ sísun tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ náà. Yóo yọ́ gbogbo ọ̀rá akọ mààlúù tí ó fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ kúrò, ati gbogbo ọ̀rá tí ó bo nǹkan inú rẹ̀; ati kíndìnrín rẹ̀ mejeeji, pẹlu ọ̀rá tí ó bo ibi ìbàdí ati ẹ̀dọ̀ rẹ̀ (gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń yọ wọ́n lára mààlúù tí wọn ń fi rú ẹbọ alaafia), yóo sì sun wọ́n níná lórí pẹpẹ ẹbọ sísun. Ṣugbọn awọ akọ mààlúù náà, ati gbogbo ẹran rẹ̀ ati orí rẹ̀ ati ẹsẹ̀ rẹ̀ ati nǹkan inú rẹ̀, ati ìgbẹ́ rẹ̀; pátá ni yóo gbé jáde kúrò ninu àgọ́, lọ síbìkan tí ó bá mọ́, níbi tí wọn ń da eérú sí, yóo sì kó igi jọ, yóo dáná sun ún níbẹ̀. “Tí ó bá jẹ́ pé gbogbo ìjọ eniyan Israẹli ni ó ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn tí ẹ̀ṣẹ̀ náà kò hàn sí ìjọ eniyan, tí wọ́n bá ṣe ọ̀kan ninu àwọn ohun gbogbo tí OLUWA ti pa láṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ ṣe, tí wọ́n sì jẹ̀bi, nígbà tí wọ́n bá mọ ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá, tí wọ́n sì rí àṣìṣe wọn, gbogbo ìjọ eniyan náà yóo fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, wọn yóo fà á wá síbi Àgọ́ Àjọ. Àwọn àgbààgbà ninu àwọn eniyan náà yóo gbé ọwọ́ wọn lé orí akọ mààlúù yìí níwájú OLUWA, wọn óo sì pa á níbẹ̀. Lẹ́yìn náà ni alufaa tí a fi òróró yàn yóo mú ninu ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù yìí wá sinu Àgọ́ Àjọ. Yóo sì ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, yóo wọ́n ọn sílẹ̀ nígbà meje níwájú OLUWA, níwájú aṣọ ìbòjú tí ó wà níbi mímọ́. Yóo mú ninu ẹ̀jẹ̀ tí ó kù, yóo fi sára àwọn ìwo pẹpẹ tí ó wà níwájú OLUWA ninu Àgọ́ Àjọ, yóo sì da ẹ̀jẹ̀ yòókù sílẹ̀ ní ìdí pẹpẹ ẹbọ sísun tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. Yóo yọ gbogbo ọ̀rá rẹ̀ yóo sì sun ún lórí pẹpẹ. Bí ó ti ṣe akọ mààlúù tí wọ́n fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni yóo ṣe akọ mààlúù yìí pẹlu. Alufaa yóo ṣe ètùtù fún wọn, OLUWA yóo sì dáríjì wọ́n. Lẹ́yìn náà, alufaa yóo gbé mààlúù yìí jáde kúrò ninu àgọ́, yóo sì sun ún bí ó ti sun mààlúù ti àkọ́kọ́; ó jẹ́ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo ìjọ eniyan náà. “Bí ìjòyè kan bá dẹ́ṣẹ̀, tí ó ṣèèṣì ṣe ọ̀kankan ninu àwọn ohun tí OLUWA Ọlọrun rẹ̀ pa láṣẹ pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe, tí ó sì jẹ̀bi, nígbà tí wọ́n bá fi ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá yìí hàn án, yóo mú òbúkọ kan tí kò ní àbààwọ́n wá, yóo fi rúbọ. Yóo gbé ọwọ́ lé orí òbúkọ yìí, yóo sì pa á níbi tí wọ́n ti máa ń pa ẹran ẹbọ sísun níwájú OLUWA; ó jẹ́ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Alufaa yóo ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹran tí wọ́n fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ yìí yóo fi sí ara àwọn ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun; yóo sì da ẹ̀jẹ̀ yòókù sílẹ̀ nídìí pẹpẹ. Yóo sun gbogbo ọ̀rá òbúkọ náà lórí pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rá ẹran tí wọ́n bá fi rú ẹbọ alaafia. Bẹ́ẹ̀ ni alufaa yóo ṣe ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, OLUWA yóo sì dáríjì í. “Bí ẹnìkan lásán ninu àwọn eniyan náà bá ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀, tí ó ṣe ọ̀kan ninu àwọn ohun tí OLUWA ti pa láṣẹ pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe, tí ó sì jẹ̀bi, lẹ́yìn tí wọ́n bá fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó dá hàn án, yóo mú abo ewúrẹ́ tí kò ní àbààwọ́n wá, yóo fi rúbọ fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá. Yóo gbé ọwọ́ lé orí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ yìí, yóo sì pa á, níbi tí wọ́n ti ń rú ẹbọ sísun. Alufaa yóo sì ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, yóo fi sí ara ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun, yóo sì da ẹ̀jẹ̀ yòókù sí ìdí pẹpẹ. Yóo yọ gbogbo ọ̀rá ewúrẹ́ náà, bí wọ́n ti ń yọ ọ̀rá ẹran tí wọ́n bá fi rú ẹbọ alaafia, alufaa yóo sì sun ún níná lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ olóòórùn dídùn sí OLUWA. Alufaa yóo ṣe ètùtù fún un, OLUWA yóo sì dáríjì í. “Bí ó bá jẹ́ pé, aguntan ni ó mú wá fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ó níláti jẹ́ abo aguntan tí kò ní àbààwọ́n. Kí ó gbé ọwọ́ lórí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ yìí, kí ó sì pa á fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń pa ẹran tí wọ́n bá fẹ́ fi rú ẹbọ sísun. Lẹ́yìn náà alufaa yóo yán ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ náà sí ara ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun, yóo wá da ẹ̀jẹ̀ yòókù sídìí pẹpẹ. Yóo yọ́ gbogbo ọ̀rá rẹ̀, bí wọ́n ti ń yọ́ ọ̀rá ẹran tí wọ́n bá fi rú ẹbọ alaafia. Alufaa yóo kó o lé orí ẹbọ náà, yóo sì fi iná sun ún lórí pẹpẹ fún OLUWA. Alufaa yóo ṣe ètùtù fún un nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá, OLUWA yóo sì dáríjì í. “Bí ẹnìkan bá dẹ́ṣẹ̀, nípa pé ó gbọ́ tí wọn ń kéde láàrin àwùjọ pé, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀ nípa ọ̀ràn kan jáde wá láti jẹ́rìí, bí ó bá mọ ohunkohun nípa ọ̀ràn náà, kì báà jẹ́ pé ó rí i ni, tabi wọ́n sọ ohunkohun fún un nípa rẹ̀ ni, tí ó bá dákẹ́, tí kò sọ ohunkohun, yóo jẹ̀bi. “Tabi bí ẹnikẹ́ni bá fi ọwọ́ kan ohunkohun tí ó jẹ́ aláìmọ́, kì báà jẹ́ òkú ẹranko tí ó jẹ́ aláìmọ́ ni, tabi òkú ẹran ọ̀sìn tí ó jẹ́ aláìmọ́, tabi òkú ohunkohun tí ń fàyà fà nílẹ̀ tí ó jẹ́ aláìmọ́, bí kò tilẹ̀ mọ̀, sibẹ òun pàápàá di aláìmọ́, ó sì jẹ̀bi. “Tabi bí ó bá fara kan ohun aláìmọ́ kan lára eniyan, ohun yòówù kí ohun náà jẹ́, ó ti sọ ẹni náà di aláìmọ́, bí irú ohun bẹ́ẹ̀ bá pamọ́ fún un, ìgbà yòówù tí ó bá mọ̀, ó jẹ̀bi. “Tabi bí ẹnikẹ́ni bá fi ẹnu ara rẹ̀ búra láìronú, kì báà jẹ́ láti ṣe ibi ni, tabi láti ṣe rere, irú ìbúra kíbùúra tí eniyan lè ṣe láìmọ̀, nígbà tí ó bá mọ̀, ó di ẹlẹ́bi. “Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá jẹ̀bi ọ̀kankan ninu àwọn ohun tí a ti dárúkọ wọnyi, kí ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, kí ó sì mú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wá sọ́dọ̀ OLUWA fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá. Kí ó mú abo ọ̀dọ́ aguntan, tabi ti ewúrẹ́ wá fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, alufaa yóo sì ṣe ètùtù fún un nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. “Bí kò bá ní agbára láti mú ọ̀dọ́ aguntan wá, ohun tí ó tún lè mú tọ OLUWA wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni àdàbà meji tabi ọmọ ẹyẹlé meji, ọ̀kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ekeji fún ẹbọ sísun. Kí ó kó wọn wá sọ́dọ̀ alufaa, kí alufaa sì fi ekinni rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Lílọ́ ni kí alufaa lọ́ ọ lọ́rùn, ṣugbọn kí ó má fà á lọ́rùn tu. Kí alufaa wọ́n díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ náà sí ara pẹpẹ, kí ó ro gbogbo ẹ̀jẹ̀ yòókù sí ìdí pẹpẹ, ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni. Lẹ́yìn náà yóo fi ẹyẹ keji rú ẹbọ sísun, gẹ́gẹ́ bí ìlànà. Bẹ́ẹ̀ ni alufaa yóo ṣe ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀, OLUWA yóo sì dáríjì í. “Ṣugbọn bí kò bá ní agbára láti mú àdàbà meji tabi ọmọ ẹyẹlé meji wá, ohun tí yóo mú wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá ni, ìdámẹ́wàá ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, kí ó má fi òróró tabi turari olóòórùn dídùn sórí rẹ̀, nítorí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni. Kí ó gbé ìyẹ̀fun náà tọ alufaa wá, kí alufaa bu ẹ̀kúnwọ́ kan ninu rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí, kí ó sì fi rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ sí OLUWA, ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni. Bẹ́ẹ̀ ni alufaa yóo ṣe ètùtù fún un nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, nítorí pé ó ṣe ọ̀kan ninu àwọn ohun tí OLUWA pa láṣẹ pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe, OLUWA yóo sì dáríjì í. Ìyẹ̀fun yòókù yóo di ti alufaa, gẹ́gẹ́ bí ti ẹbọ ohun jíjẹ.” OLUWA sọ fún Mose pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀ nípa pé kò san àwọn nǹkan tíí ṣe ti OLUWA fún OLUWA, ohun tí yóo mú wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi fún OLUWA ni: àgbò kan tí kò ní àbààwọ́n, láti inú agbo aguntan rẹ̀, ìwọ̀n tí wọ́n fi ń wọn fadaka ninu ilé OLUWA ni wọn yóo lò láti fi díyelé àgbò náà; ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi ni. Yóo san ohun tí ó yẹ kí ó san fún OLUWA tí kò san, pẹlu èlé ìdámárùn-ún rẹ̀ fún alufaa, alufaa yóo sì fi àgbò ẹbọ ẹ̀bi náà ṣe ètùtù fún un, a óo sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì í. “Bí ẹnikẹ́ni bá dẹ́ṣẹ̀, tí ó ṣe ọ̀kan ninu àwọn nǹkan tí OLUWA pa láṣẹ pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò mọ̀, sibẹ ó jẹ̀bi, yóo sì san ìtanràn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Kí ó mú àgbò kan tí kò ní àbààwọ́n wá sí ọ̀dọ̀ alufaa, ó gbọdọ̀ rí i pé àgbò yìí tó iye tí wọn ń ra ẹran fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, alufaa yóo ṣe ètùtù fún un fún àṣìṣe rẹ̀ tí ó ṣèèṣì ṣe, OLUWA yóo sì dáríjì í. Ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá sí OLUWA ni.” OLUWA sọ fún Mose, pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA nípa ṣíṣe èyíkéyìí ninu nǹkan wọnyi: kì báà jẹ́ pé ó kọ̀ láti dá ohun tí aládùúgbò rẹ̀ fi dógò pada ni, tabi pé ó ja aládùúgbò rẹ̀ lólè ni, tabi pé ó rẹ́ ẹ jẹ ni, tabi pé ó rí nǹkan rẹ̀ tí ó sọnù he, tí ó sì ṣe bí ẹni pé òun kò rí i, tabi tí ó búra èké nípa ohunkohun, ẹ̀ṣẹ̀ ni ó dá. Bí ẹnikẹ́ni bá dá irú ẹ̀ṣẹ̀ yìí, kí ó dá ohun tí ó jí pada, tabi ohun tí ó fi ìrẹ́jẹ gbà, tabi ohun tí wọ́n fi dógò lọ́dọ̀ rẹ̀, tabi ohun tí ó sọnù tí ó rí he, tabi ohunkohun tí ó ti búra èké sí. Kí ó san án pé pérépéré kí ó sì fi ìdámárùn-ún lé e, nígbà tí ó bá dá ohun náà pada fún olúwarẹ̀, ní ọjọ́ tí yóo bá rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi. Kí ó mú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi tọ alufaa wá, ohun ìrúbọ náà ni àgbò kan tí kò ní àbààwọ́n, kí ó rí i pé àgbò náà tó iye tí eniyan lè ra ẹran fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi. Alufaa yóo ṣe ètùtù fún ẹni náà níwájú OLUWA, OLUWA yóo sì dárí ohunkohun tí ó bá ṣe jì í.” OLUWA sọ fún Mose pé, “Pa á láṣẹ fún Aaroni, ati àwọn ọmọ rẹ̀ pé, èyí ni òfin tí ó jẹmọ́ ti ẹbọ sísun: ẹbọ sísun níláti wà lórí ààrò lórí pẹpẹ ní gbogbo òru títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, iná sì níláti máa jò lórí pẹpẹ náà ní gbogbo ìgbà. Kí alufaa wọ ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ funfun rẹ̀, ati ṣòkòtò aṣọ funfun, kí ó kó eérú ẹbọ tí ó ti fi iná sun kúrò lórí pẹpẹ, kí ó sì dà á sí ibìkan. Lẹ́yìn náà, kí ó bọ́ aṣọ iṣẹ́ alufaa rẹ̀ kí ó sì wọ aṣọ mìíràn, kí ó wá ru eérú náà jáde kúrò ninu àgọ́ sí ibi mímọ́ kan. Kí iná orí pẹpẹ náà sì máa jó, kò gbọdọ̀ kú nígbà kan. Kí alufaa máa kó igi sí i ní àràárọ̀; kí ó máa to ẹbọ sísun lé e lórí, orí rẹ̀ ni yóo sì ti máa sun ọ̀rá ẹran tí ó bá fi rú ẹbọ alaafia. Iná orí pẹpẹ náà gbọdọ̀ máa jó nígbà gbogbo, kò gbọdọ̀ kú. “Èyí ni òfin tí ó jẹmọ́ ẹbọ ohun jíjẹ. Àwọn ọmọ Aaroni ni yóo máa rúbọ náà níwájú pẹpẹ, níwájú OLUWA. Ọ̀kan ninu wọn yóo bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun kan ninu ẹbọ ohun jíjẹ náà, pẹlu òróró ati turari tí ó wà lórí rẹ̀, yóo sì sun ún gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí lórí pẹpẹ, ẹbọ olóòórùn dídùn sí OLUWA ni. Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóo jẹ ìyókù, láì fi ìwúkàrà sí i. Ibi mímọ́ kan ninu àgbàlá Àgọ́ Àjọ ni wọ́n ti gbọdọ̀ jẹ ẹ́. Wọn kò gbọdọ̀ fi ìwúkàrà sí i, bí wọ́n bá fi ṣe burẹdi, èmi ni mo fún wọn, gẹ́gẹ́ bí ìpín tiwọn ninu ẹbọ sísun mi; ó jẹ́ ohun mímọ́ jùlọ, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ti ìmúkúrò ẹ̀bi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ọkunrin ninu àwọn ọmọ Aaroni lè jẹ ninu rẹ̀, èyí ni ìlànà mi títí ayérayé láàrin arọmọdọmọ yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan ẹbọ wọnyi yóo di mímọ́.” OLUWA sọ fún Mose pé, “Ẹbọ tí àwọn ọmọ Aaroni yóo máa rú, ní ọjọ́ tí wọ́n bá fi wọ́n joyè alufaa nìyí: Ìdámẹ́wàá ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ, ìdajì rẹ̀ ní òwúrọ̀, ìdajì tí ó kù ní àṣáálẹ́. Kí wọ́n fi òróró po ìyẹ̀fun náà dáradára, kí wọ́n tó yan án lórí ààrò, lẹ́yìn náà kí wọ́n rún un gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ, kí wọ́n sì fi rú ẹbọ olóòórùn dídùn sí OLUWA. Ẹni tí wọ́n bá yàn sí ipò olórí alufaa lẹ́yìn Aaroni ninu àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóo máa rú ẹbọ yìí sí OLUWA gẹ́gẹ́ bí ìlànà títí lae, gbogbo ìyẹ̀fun náà ni yóo fi rú ẹbọ sísun. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ ninu ìyẹ̀fun ẹbọ ohun jíjẹ ti alufaa, gbogbo rẹ̀ ni kí wọ́n fi rú ẹbọ sísun.” OLUWA sọ fún Mose pé, “Sọ fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ pé, èyí ni òfin tí ó jẹmọ́ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, níbi tí wọ́n ti ń pa ẹran fún ẹbọ sísun, ni kí wọ́n ti máa pa ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ pẹlu, níwájú OLUWA; ó jẹ́ ohun mímọ́ jùlọ. Alufaa tí ó bá fi rúbọ fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni yóo jẹ ẹ́; níbi mímọ́, ninu àgbàlá Àgọ́ Àjọ ni kí ó ti jẹ ẹ́. Ohunkohun tí ó bá ti kan ẹran rẹ̀ di mímọ́; nígbà tí wọ́n bá sì ta lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sára aṣọ kan, ibi mímọ́ ni wọ́n ti gbọdọ̀ fọ aṣọ náà. Fífọ́ ni wọ́n sì gbọdọ̀ fọ́ ìkòkò amọ̀ tí wọ́n bá fi sè é, ṣugbọn tí ó bá jẹ́ pé ìkòkò idẹ ni wọ́n fi sè é, wọ́n gbọdọ̀ fi omi fọ̀ ọ́, kí wọ́n sì ṣàn án nù dáradára. Èyíkéyìí ninu àwọn ọmọ alufaa tí ó bá jẹ́ ọkunrin lè jẹ ninu ohun ìrúbọ yìí; ó jẹ́ ohun mímọ́ jùlọ. Ṣugbọn bí wọ́n bá mú ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sinu Àgọ́ Àjọ, tí wọ́n bá lò ó fún ètùtù ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ ẹran náà, sísun ni wọ́n gbọdọ̀ sun ún. “Èyí ni òfin ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi. Ó jẹ́ mímọ́ jùlọ; níbi tí wọ́n ti pa ẹran ẹbọ sísun ni wọ́n gbọdọ̀ ti pa ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, wọn yóo sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí ara pẹpẹ yípo. Gbogbo ọ̀rá ara rẹ̀ ni wọ́n gbọdọ̀ fi rúbọ; ìrù tí ó lọ́ràá ati ọ̀rá tí ó bo ìfun rẹ̀, àwọn kíndìnrín rẹ̀ ati ọ̀rá tí ó wà lára wọn níbi ìbàdí ati àwọn tí ó bo ẹ̀dọ̀ ni wọn óo mú pẹlu àwọn kíndìnrín náà. Alufaa yóo sun wọ́n lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun fún OLUWA, ó jẹ́ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi. Gbogbo ọkunrin, lára àwọn alufaa lè jẹ ninu rẹ̀, wọ́n gbọdọ̀ jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́ nítorí pé ó jẹ́ mímọ́ jùlọ. “Ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi dàbí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, òfin kan ṣoṣo ni ó de oríṣìí ẹbọ mejeeji: òfin náà sì ni pé alufaa tí ó fi ṣe ètùtù ni ó ni ẹbọ náà. Alufaa tí ó bá rú ẹbọ sísun fún eniyan ni ó ni awọ ẹran ẹbọ sísun náà. Gbogbo ẹbọ ohun jíjẹ tí a yan ati gbogbo èyí tí a sè ninu apẹ tabi ninu àwo pẹrẹsẹ jẹ́ ti alufaa tí ó fi wọ́n rúbọ. Gbogbo ẹbọ ohun jíjẹ tí a fi òróró pò tabi tí ó jẹ́ ìyẹ̀fun, yóo wà fún àwọn ọmọ Aaroni bákan náà. “Èyí ni òfin ẹbọ alaafia, tí eniyan lè rú sí OLUWA. Tí ó bá rú u fún ìdúpẹ́, yóo rú u pẹlu àkàrà tí kò ní ìwúkàrà, tí a fi òróró pò, ati àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí kò ní ìwúkàrà, tí a da òróró lé lórí, pẹlu àkàrà tí a fi ìyẹ̀fun kíkúnná ṣe, tí a fi òróró pò dáradára. Ẹni tí ó bá rú ẹbọ alaafia fún ìdúpẹ́ yóo mú ẹbọ rẹ̀ wá pẹlu àkàrà tí ó ní ìwúkàrà. Kí ó yọ àkàrà kọ̀ọ̀kan kúrò lára ẹbọ kọ̀ọ̀kan, kí ó fi rúbọ sí OLUWA; yóo jẹ́ ti alufaa tí ó wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran ẹbọ alaafia náà sára pẹpẹ. Wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ ẹran ẹbọ alaafia tí ó fi ṣe ẹbọ ọpẹ́ tán ní ọjọ́ tí ó bá rú ẹbọ náà, kò gbọdọ̀ ṣẹ́kù di ọjọ́ keji. “Ṣugbọn bí ẹbọ ọrẹ rẹ̀ bá jẹ́ ti ẹ̀jẹ́ tabi ọrẹ àtinúwá, wọ́n gbọdọ̀ jẹ ẹ́ ní ọjọ́ náà, ṣugbọn bí ó bá ṣẹ́kù, wọ́n lè jẹ ẹ́ ní ọjọ́ keji; ṣugbọn bí ó bá ṣẹ́kù di ọjọ́ kẹta, sísun ni kí ó sun ún. Bí wọ́n bá jẹ ninu ẹran ẹbọ alaafia tí ó bá ṣẹ́kù di ọjọ́ kẹta, ẹbọ náà kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lọ́wọ́ ẹni tí ó bá rú u, a kò ní kọ ọ́ sílẹ̀ fún un, nítorí pé ohun ìríra ni, ẹni tí ó bá jẹ ẹ́ ni yóo ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ ẹran tí ó bá kan ohun àìmọ́ kan, sísun ni ẹ gbọdọ̀ sun irú ẹran bẹ́ẹ̀. “Gbogbo àwọn tí wọ́n bá jẹ́ mímọ́ lè jẹ àwọn ẹran yòókù, ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ lára ẹran tí a fi rú ẹbọ alaafia sí OLUWA, ní àkókò tí òun fúnra rẹ̀ jẹ́ aláìmọ́, a óo yọ ọ́ kúrò lára àwọn eniyan Ọlọrun. Bí ẹnikẹ́ni bá fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kan, ìbáà ṣe ohun àìmọ́ ti eniyan, tabi ti ẹranko tabi ohun ìríra kan, lẹ́yìn náà tí ó wá jẹ ninu ẹran tí a fi rú ẹbọ alaafia sí OLUWA, a óo yọ ẹni náà kúrò lára àwọn eniyan Ọlọrun.” OLUWA ní kí Mose sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ọ̀rákọ́ràá, ìbáà jẹ́ ti mààlúù tabi ti aguntan tabi ti ewúrẹ́. Ẹ lè lo ọ̀rá ẹran tí ó kú fúnra rẹ̀ ati ọ̀rá èyí tí ẹranko burúkú pa, fún ohun mìíràn, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́. Nítorí pé a óo yọ ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ọ̀rá ẹran tí a fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA, kúrò lára àwọn eniyan Ọlọrun. Siwaju sí i, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ní gbogbo ibùgbé yín, bí ó ti wù kí ó rí; ìbáà jẹ́ ti ẹyẹ tabi ti ẹranko. A óo yọ ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ̀jẹ̀ kúrò lára àwọn eniyan Ọlọrun.” OLUWA ní kí Mose sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ rú ẹbọ alaafia sí OLUWA, yóo mú ẹbọ náà wá fún OLUWA. Ninu ẹbọ alaafia rẹ̀, ni yóo ti fi ọwọ́ ara rẹ̀ mú ẹbọ sísun wá fún OLUWA. Ọ̀rá ẹran náà pẹlu àyà rẹ̀ ni yóo mú wá. Alufaa yóo fi àyà ẹran náà gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA. Alufaa yóo sun ọ̀rá ẹran náà lórí pẹpẹ, ṣugbọn àyà rẹ̀ yóo jẹ́ ti Aaroni ati ti àwọn ọmọ rẹ̀. Ẹ óo fún alufaa ní itan ọ̀tún rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ lára ẹbọ alaafia yín. Èyíkéyìí ninu àwọn ọmọ Aaroni tí ó bá fi ẹ̀jẹ̀ ati ọ̀rá ẹran náà rúbọ ni ó ni itan ọ̀tún ẹran náà gẹ́gẹ́ bí ìpín tirẹ̀. Nítorí mo ti gba àyà tí a fì ati itan tí a fi rúbọ lọ́wọ́ àwọn eniyan Israẹli lára ọrẹ ẹbọ alaafia wọn, yóo sì jẹ́ ti Aaroni, alufaa, ati àwọn ọmọ rẹ̀. Èyí ni ìpín tiwọn láti ọ̀dọ̀ àwọn eniyan Israẹli. Ìpín Aaroni ni ati ti àwọn ọmọ rẹ̀, lára ẹbọ sísun tí a rú sí OLUWA, àní ẹbọ tí a yà sọ́tọ̀ fún wọn, ní ọjọ́ tí a mú wọn wá siwaju OLUWA láti máa ṣe iṣẹ́ alufaa. Ní ọjọ́ tí a fi òróró yàn wọ́n, ni OLUWA ti pàṣẹ fún àwọn eniyan Israẹli láti máa fún wọn, ó jẹ́ ìpín tiwọn láti ìrandíran.” Òfin ẹbọ sísun ni, ati ti ẹbọ ohun jíjẹ, ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, ti ẹbọ ìyàsímímọ́, ati ti ẹbọ alaafia; tí OLUWA paláṣẹ fún Mose, ní orí òkè Sinai ní ọjọ́ tí ó pàṣẹ fún àwọn eniyan Israẹli láti mú ẹbọ wọn wá fún òun OLUWA ninu aṣálẹ̀ Sinai. OLUWA sọ fún Mose pé, “Mú Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin ati ẹ̀wù iṣẹ́ alufaa wọn, ati òróró ìyàsímímọ́, ati akọ mààlúù fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati àgbò meji náà, ati agbọ̀n burẹdi tí kò ní ìwúkàrà. Lẹ́yìn náà, kó gbogbo àwọn eniyan náà jọ sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.” Mose bá pe gbogbo ìjọ eniyan náà jọ sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un. Ó sọ fún wọn pé, “Ohun tí OLUWA pàṣẹ pé ẹ gbọdọ̀ ṣe nìyí.” Ó mú Aaroni, ati àwọn ọmọ rẹ̀ jáde, ó fi omi wẹ̀ wọ́n. Ó gbé ẹ̀wù náà wọ Aaroni, ó sì dì í ní àmùrè rẹ̀, ó gbé aṣọ àwọ̀kanlẹ̀ wọ̀ ọ́ ati efodu rẹ̀, ó sì fi ọ̀já efodu tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà dáradára sí lára dì í lámùrè. Ó mú ìgbàyà, ó so ó mọ́ ọn láyà, ó sì fi Urimu ati Tumimu sí ara ìgbàyà náà. Ó fi fìlà dé e lórí, ó fi ohun ọ̀ṣọ́ wúrà, adé mímọ́ tíí ṣe àmì ìyàsímímọ́, sí iwájú fìlà náà, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún Mose. Mose gbé òróró ìyàsímímọ́, ó ta á sí gbogbo ara Àgọ́ náà ati ohun gbogbo tí ó wà ninu rẹ̀, ó sì yà wọ́n sí mímọ́. Ó mú lára òróró náà ó wọ́n ọn sí ara pẹpẹ nígbà meje, ó ta á sórí pẹpẹ náà ati gbogbo àwọn ohun èlò tí wọ́n wà níbẹ̀, ati agbada omi ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀; ó fi yà wọ́n sí mímọ́. Ó ta díẹ̀ ninu òróró náà sí Aaroni lórí láti yà á sí mímọ́. Mose kó àwọn ọmọ Aaroni, ó wọ̀ wọ́n lẹ́wù, ó sì dì wọ́n ní àmùrè, ó dé wọn ní fìlà, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un. Lẹ́yìn náà, ó mú mààlúù ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ jáde, Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin gbé ọwọ́ lé e lórí. Mose pa mààlúù náà, ó gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ó ti ìka bọ̀ ọ́, ó sì fi sí ara àwọn ìwo pẹpẹ yípo, ó fi yà wọ́n sí mímọ́. Ó da ẹ̀jẹ̀ yòókù sídìí pẹpẹ fún ètùtù, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe yà wọ́n sí mímọ́. Lẹ́yìn náà, ó mú gbogbo ọ̀rá tí ó bo àwọn nǹkan inú mààlúù náà, ati ẹ̀dọ̀ rẹ̀, ati kíndìnrín rẹ̀ mejeeji, pẹlu ọ̀rá tó wà lára wọn, ó sun wọ́n lórí pẹpẹ. Ṣugbọn ó dáná sun ara ẹran akọ mààlúù náà, ati awọ rẹ̀, ati ìgbẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn ibùdó náà, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un. Lẹ́yìn náà, Mose fa àgbò ẹbọ sísun kalẹ̀, Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin sì gbé ọwọ́ wọn lé e lórí. Lẹ́yìn náà, Mose pa á, ó da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sórí pẹpẹ yípo. Wọ́n gé ẹran àgbò náà sí wẹ́wẹ́, ó sun gbogbo rẹ̀ pẹlu orí rẹ̀ ati ọ̀rá rẹ̀ lórí pẹpẹ. Nígbà tí ó fọ nǹkan inú rẹ̀ ati ẹsẹ̀ rẹ̀, ó fi gbogbo rẹ̀ rú ẹbọ sísun, ẹbọ olóòórùn dídùn tí a fi iná sun sí OLUWA, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. Lẹ́yìn náà, ó fa àgbò keji kalẹ̀, èyí tí í ṣe àgbò ìyàsímímọ́. Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ọwọ́ wọn lé e lórí. Lẹ́yìn náà Mose pa á, ó tọ́ ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ó fi kan etí ọ̀tún Aaroni, ati àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ati àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀. Wọ́n mú àwọn ọmọ Aaroni náà jáde, Mose tọ́ ninu ẹ̀jẹ̀ náà, ó fi kan etí ọ̀tún wọn, ati àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, ati àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún wọn, ó sì da ẹ̀jẹ̀ yòókù sórí pẹpẹ yípo. Lẹ́yìn náà, ó mú ọ̀rá àgbò náà, ati ọ̀rá ìrù rẹ̀, ati gbogbo ọ̀rá tí ó bo àwọn nǹkan inú rẹ̀, ati ẹ̀dọ̀ rẹ̀, ati kíndìnrín rẹ̀ mejeeji pẹlu ọ̀rá tí ó wà lára wọn, ati itan ọ̀tún rẹ̀. Ó mú burẹdi dídùn kan tí kò ní ìwúkàrà ninu, ninu agbọ̀n burẹdi tí ó wà níwájú OLUWA, ati burẹdi olóròóró kan tí kò ní ìwúkàrà ninu ati burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kan, ó kó wọn lé orí ọ̀rá náà ati itan ọ̀tún àgbò náà. Ó kó gbogbo rẹ̀ lé Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, wọ́n sì fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA. Lẹ́yìn náà, Mose gbà á kúrò lọ́wọ́ wọn, ó sun wọ́n lórí pẹpẹ, pẹlu ẹbọ sísun bí ẹbọ ìyàsímímọ́, ẹbọ olóòórùn dídùn, tí a fi iná sun sí OLÚWA. Mose mú igẹ̀ àyà àgbò náà, ó fì í gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA. Òun ni ìpín Mose ninu àgbò ìyàsímímọ́ yìí, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún un. Lẹ́yìn náà, Mose mú ninu òróró ìyàsímímọ́, ati díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ tí ó wà lórí pẹpẹ, ó wọ́n ọn sí ara Aaroni ati aṣọ rẹ̀, ati sí ara àwọn ọmọ rẹ̀, ati aṣọ wọn. Bẹ́ẹ̀ ló ṣe ya Aaroni ati àwọn aṣọ rẹ̀ sí mímọ́, ati àwọn ọmọ rẹ̀, tàwọn taṣọ wọn. Mose bá sọ fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin pé, “Ẹ lọ bọ ẹran àgbò náà lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ kí ẹ sì jẹ ẹ́ níbẹ̀, pẹlu burẹdi tí ó wà ninu agbọ̀n ọrẹ ẹbọ ìyàsímímọ́, gẹ́gẹ́ bí mo ti pa á láṣẹ pé: ‘Aaroni ati ọmọ rẹ̀ ni kí wọ́n máa jẹ ẹ́’. Ohunkohun tí ó bá kù ninu ẹran ati burẹdi náà, ẹ dáná sun ún. Ẹ kò sì gbọdọ̀ jáde kúrò ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ náà fún ọjọ́ meje títí tí ọjọ́ ètò ìyàsímímọ́ yín yóo fi pé; nítorí ọjọ́ meje gbáko ni ètò ìyàsímímọ́ yín yóo gbà. Gbogbo bí a ti ṣe lónìí ni OLUWA pa láṣẹ pé kí á ṣe, láti ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yín. Lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ ni kí ẹ wà tọ̀sán-tòru fún ọjọ́ meje, kí ẹ máa ṣe àwọn ohun tí OLUWA pa láṣẹ fun yín, kí ẹ má baà kú; nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni ó pa á láṣẹ fún mi.” Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ sì ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ láti ẹnu Mose. Ní ọjọ́ kẹjọ, Mose pe Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ati àwọn àgbààgbà Israẹli; ó wí fún Aaroni pé, “Mú ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati àgbò kan fún ẹbọ sísun kí o sì fi wọ́n rúbọ níwájú OLUWA. Àwọn ẹran mejeeji yìí kò gbọdọ̀ ní àbààwọ́n. Sì sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, ‘Ẹ mú òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ọmọ mààlúù kan ati ọ̀dọ́ aguntan kan fún ẹbọ sísun, kí àwọn mejeeji jẹ́ ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, wọn kò sì gbọdọ̀ ní àbààwọ́n. Sì mú akọ mààlúù kan ati àgbò kan fún ẹbọ alaafia, kí ẹ fi wọ́n rúbọ níwájú OLUWA pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ tí a fi òróró pò, nítorí pé OLUWA yóo fi ara hàn yín lónìí.’ ” Wọ́n mú àwọn ohun tí Mose paláṣẹ wá siwaju Àgọ́ Àjọ, gbogbo ìjọ eniyan sì dúró níwájú OLUWA. Mose sọ fún wọn pé, “Ohun tí OLUWA paláṣẹ fun yín láti ṣe nìyí, ògo OLUWA yóo hàn sí yín.” Lẹ́yìn náà, Mose sọ fún Aaroni pé, “Súnmọ́ ibi pẹpẹ, kí o sì rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, ati ẹbọ sísun rẹ, kí o sì ṣe ètùtù fún ara rẹ ati fún àwọn eniyan náà. Gbé ẹbọ àwọn eniyan náà wá, kí o sì ṣe ètùtù fún wọn, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ.” Aaroni bá súnmọ́ ibi pẹpẹ náà, ó pa ọ̀dọ́ mààlúù fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀. Àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá fún un, ó sì ti ìka bọ̀ ọ́, ó fi kan ara ìwo pẹpẹ, ó sì da ẹ̀jẹ̀ yòókù sí ìdí pẹpẹ. Ó mú ọ̀rá ọ̀dọ́ mààlúù náà, ati àwọn kíndìnrín rẹ̀ ati ẹ̀dọ̀ rẹ̀ kúrò ninu ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ó sun wọ́n lórí pẹpẹ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. Ó sì dáná sun ẹran ati awọ mààlúù náà lẹ́yìn ibùdó. Ó pa ẹran ẹbọ sísun, àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ, ó sì dà á sí ara pẹpẹ yípo. Wọ́n gbé ẹran ẹbọ sísun tí wọ́n ti gé sí wẹ́wẹ́, ati orí rẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ, ó sì sun wọ́n lórí pẹpẹ. Ó fọ àwọn nǹkan inú rẹ̀, ati ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì sun wọ́n papọ̀ pẹlu ẹbọ sísun lórí pẹpẹ. Lẹ́yìn náà ó fa ẹran ẹbọ sísun àwọn eniyan náà kalẹ̀, ó mú ewúrẹ́ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan náà, ó pa á, ó sì fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ti àkọ́kọ́. Ó gbé ẹran ẹbọ sísun wá, ó sì fi rúbọ gẹ́gẹ́ bí ìlànà. Ó gbé ẹbọ ohun jíjẹ wá, ó bu ẹ̀kúnwọ́ kan ninu rẹ̀, ó sì sun ún lórí pẹpẹ ní ẹ̀gbẹ́ ẹbọ sísun ti òwúrọ̀. Ó pa akọ mààlúù ati àgbò ẹbọ alaafia fún àwọn eniyan, àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, ó sì dà á sórí pẹpẹ náà yípo. Ó mú ọ̀rá akọ mààlúù, ati ti àgbò náà, pẹlu ìrù wọn tí ó lọ́ràá, ati ọ̀rá tí ó bo àwọn nǹkan inú wọn, ati kíndìnrín ati ẹ̀dọ̀ wọn. Ó kó gbogbo ọ̀rá náà lé orí igẹ̀ ẹran náà; ó sun ún lórí pẹpẹ. Ṣugbọn ó mú àwọn igẹ̀ ẹran náà ati itan ọ̀tún wọn, ó fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA, bí Mose ti pa á láṣẹ. Lẹ́yìn náà, Aaroni kọjú sí àwọn eniyan náà, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó sì súre fún wọn. Lẹ́yìn náà, ó sọ̀kalẹ̀ láti ibi tí ó ti ń rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia. Mose ati Aaroni bá wọ inú Àgọ́ Àjọ lọ. Nígbà tí wọ́n jáde, wọ́n súre fún àwọn eniyan náà, ògo OLUWA sì yọ sí gbogbo wọn. Lójijì, iná ṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ OLUWA wá, ó jó ẹbọ sísun náà, ati ọ̀rá tí ó wà lórí pẹpẹ. Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan rí i, wọ́n kígbe sókè, wọ́n sì dojúbolẹ̀. Àwọn ọmọ Aaroni meji kan, ọkunrin, tí wọn ń jẹ́ Nadabu ati Abihu, mú àwo turari wọn, olukuluku fọn ẹ̀yinná sinu tirẹ̀, wọ́n da turari lé e lórí, wọ́n sì fi rúbọ níwájú OLUWA, ṣugbọn iná yìí kì í ṣe irú iná mímọ́ tí OLUWA pa láṣẹ fún wọn. OLUWA bá rán iná kan jáde, iná náà jó wọn pa, wọ́n sì kú níwájú OLUWA. Mose bá pe Aaroni, ó wí fún un pé, “Ohun tí OLUWA wí nìyí, ‘N óo fi ara mi hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni mímọ́ láàrin àwọn tí wọ́n jẹ́ òjíṣẹ́ mi, n óo sì gba ògo níwájú gbogbo àwọn eniyan’ ” Aaroni dákẹ́, kò sọ̀rọ̀. Mose bá pe Miṣaeli ati Elisafani, àwọn ọmọ Usieli, arakunrin Aaroni, ó ní, “Ẹ lọ gbé òkú àwọn arakunrin yín kúrò níwájú ibi mímọ́, kí ẹ sì gbé wọn jáde kúrò láàrin ibùdó.” Wọ́n bá gbé wọn tẹ̀wù tẹ̀wù kúrò láàrin ibùdó gẹ́gẹ́ bí Mose ti wí. Mose sọ fún Aaroni, ati àwọn ọmọ rẹ̀ meji, Eleasari ati Itamari pé, “Ẹ má ṣe fi irun yín sílẹ̀ játijàti, ẹ má sì ṣe fa aṣọ yín ya (láti fihàn pé ẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀), kí ẹ má baà kú, kí ibinu OLUWA má baà wá sórí gbogbo eniyan. Ṣugbọn gbogbo ilé Israẹli, àwọn eniyan yín, lè ṣọ̀fọ̀ iná tí OLUWA fi jó yín. Ẹ kò sì gbọdọ̀ jáde kúrò ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, kí ẹ má baà kú, nítorí pé òróró ìyàsímímọ́ OLUWA wà lórí yín.” Wọ́n sì ṣe bí Mose ti wí. OLUWA bá Aaroni sọ̀rọ̀, ó ní, “Nígbà tí o bá ń wọ inú Àgọ́ Àjọ lọ, ìwọ, ati àwọn ọmọ rẹ, ẹ kò gbọdọ̀ mu ọtí waini tabi ọtí líle, kí ẹ má baà kú; èyí yóo jẹ́ ìlànà títí ayé fún arọmọdọmọ yín. Ẹ gbọdọ̀ mọ ìyàtọ̀, láàrin ohun tí a yà sọ́tọ̀ fún OLUWA ati ohun tí ó wà fún ìlò gbogbo eniyan; ẹ níláti mọ ìyàtọ̀, láàrin àwọn ohun tí wọ́n jẹ́ mímọ́ ati àwọn ohun tí wọ́n jẹ́ aláìmọ́; ẹ sì níláti kọ́ àwọn eniyan Israẹli ní gbogbo ìlànà tí OLUWA ti là sílẹ̀, tí ó ní kí Mose sọ fun yín.” Mose sọ fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji tí wọ́n ṣẹ́kù, Eleasari ati Itamari, ó ní, “Ẹ gbé ohun ìrúbọ tí ó kù ninu ẹbọ ohun jíjẹ tí a fi iná sun sí OLUWA, kí ẹ sì jẹ ẹ́ lẹ́bàá pẹpẹ, láì fi ìwúkàrà sí i, nítorí pé mímọ́ jùlọ ni. Ibi mímọ́ ni kí ẹ ti jẹ ẹ́, nítorí pé òun ni ìpín yín ati ti àwọn ọmọ yín, ninu ẹbọ sísun OLUWA, nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni OLUWA pa á láṣẹ fún mi. Ṣugbọn kí ẹ jẹ igẹ̀ tí ẹ bá fi rú ẹbọ fífì ati itan ẹran tí wọ́n fi rú ẹbọ ní ibi mímọ́, ìwọ ati àwọn ọmọkunrin rẹ ati àwọn ọmọbinrin rẹ, nítorí pé ìpín tìrẹ ni, ati ti àwọn ọmọkunrin rẹ, ninu ẹbọ alaafia, tí àwọn eniyan Israẹli rú. Nígbà tí wọ́n bá mú ọ̀rá ẹran wá fún ẹbọ sísun, tí wọ́n mú itan ẹran tí wọ́n fi rúbọ, ati igẹ̀ àyà rẹ̀ fún ẹbọ fífì níwájú OLUWA, yóo máa jẹ́ tìrẹ, ati ti àwọn ọmọ rẹ, gẹ́gẹ́ bí ìpín yín títí ayé, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ.” Mose fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí nípa ewúrẹ́ tí wọ́n fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ó sì rí i pé wọ́n ti dáná sun ún. Inú bí i sí Eleasari ati Itamari, àwọn ọmọ Aaroni tí wọ́n ṣẹ́kù, ó ní, “Kí ló dé tí ẹ kò fi jẹ ẹran ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ní ibi mímọ́ nígbà tí ó jẹ́ pé, ohun tí ó mọ́ jùlọ ni, tí ó sì jẹ́ pé ẹ̀yin ni OLUWA ti fún, kí ẹ lè máa ru ẹ̀ṣẹ̀ ìjọ eniyan yìí, kí ẹ sì máa ṣe ètùtù fún wọn níwájú OLUWA. Wọn kò sì tíì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sinu ibi mímọ́, gẹ́gẹ́ bí mo ti pa á láṣẹ.” Aaroni dá Mose lóhùn pé, “Wò ó! Lónìí ni wọ́n rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹbọ sísun wọn sí OLUWA, sibẹsibẹ irú nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ sí mi. Bí ó bá jẹ́ pé mo ti jẹ ẹran ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ lónìí ni, ǹjẹ́ ẹbọ náà lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níwájú OLUWA?” Nígbà tí Mose gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, inú rẹ̀ rọ̀. OLUWA rán Mose ati Aaroni pé kí wọ́n sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, “Àwọn ẹran tí wọ́n lè jẹ lára àwọn ẹran tí wọ́n wà láyé nìwọ̀nyí: Àwọn ẹran tí wọ́n bá ya pátákò ẹsẹ̀, àwọn tí ẹsẹ̀ wọ́n là ati àwọn tí wọn ń jẹ àpọ̀jẹ. Ninu àwọn tí wọn ń jẹ àpọ̀jẹ tabi tí pátákò ẹsẹ̀ wọ́n yà, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ àwọn wọnyi: ràkúnmí, nítorí pé ó ń jẹ àpọ̀jẹ, ṣugbọn pátákò ẹsẹ̀ rẹ̀ kò yà, ó jẹ́ ohun àìmọ́ fun yín. Ati gara nítorí pé ó ń jẹ àpọ̀jẹ, ṣugbọn pátákò ẹsẹ̀ rẹ̀ kò yà, ó jẹ́ ohun àìmọ́ fun yín. Ati ehoro, nítorí pé ó ń jẹ àpọ̀jẹ, ṣugbọn pátákò ẹsẹ̀ rẹ̀ kò yà, ó jẹ́ ohun àìmọ́ fun yín. Ati ẹlẹ́dẹ̀ nítorí pé pátákò ẹsẹ̀ rẹ̀ yà, ẹsẹ̀ rẹ̀ sì yà, ṣugbọn kì í jẹ àpọ̀jẹ, ó jẹ́ ohun àìmọ́ fun yín. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran wọn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan òkú wọn, aláìmọ́ ni wọ́n. “Ninu àwọn ẹ̀dá alààyè tí ń gbé inú omi, ẹ lè jẹ àwọn wọnyi: gbogbo ohun tí ó bá ní lẹbẹ ati ìpẹ́, kì báà jẹ́ èyí tí ó ń gbé inú òkun tabi inú odò, ẹ lè jẹ wọ́n. Ṣugbọn ohunkohun tí ó ń gbé inú òkun, tabi inú odò, ninu gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè tí wọn ń káàkiri inú omi, èyíkéyìí tí kò bá ní lẹbẹ ati ìpẹ́, ohun ìríra ni fun yín. Ohun ìríra ni wọn yóo jẹ́ fun yín, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran wọn, ohun ìríra ni òkú wọn gbọdọ̀ jẹ́ fun yín pẹlu. Ohunkohun tí ó ń gbé inú omi, tí kò bá ti ní lẹbẹ ati ìpẹ́, ohun ìríra ni fun yín. “Àwọn wọnyi ni ẹ óo kà sí ohun ìríra, tí ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ninu àwọn ẹyẹ: idì, igún, ati oríṣìí àṣá kan tí ó dàbí idì, gbogbo oniruuru àṣá, gbogbo oniruuru ẹyẹ ìwò, ògòǹgò, ati ẹyẹ kan bí ẹ̀lulùú tí ń gbé aṣálẹ̀, ẹyẹ òwìwí, ẹyẹ òòyo, ati ẹyẹ kan bí igún, ògbúgbú, òfú, ati àkàlà, ẹyẹ àkọ̀, ati oniruuru yanjayanja, ẹyẹ atọ́ka, ati àdán. “Gbogbo kòkòrò tí ó ní ìyẹ́, tí ó sì ń fi ẹsẹ̀ mẹrẹẹrin rìn, ìríra ni wọ́n jẹ́ fun yín. Sibẹsibẹ ninu àwọn kòkòrò tí wọn ní ìyẹ́, tí wọn ń fi ẹsẹ̀ mẹrẹẹrin rìn, ẹ lè jẹ àwọn tí wọn bá ní tete tí wọ́n fi ń ta káàkiri lórí ilẹ̀. Ẹ lè jẹ àwọn wọnyi ninu wọn: Oríṣìíríṣìí eṣú ati oríṣìíríṣìí ìrẹ̀ ati oríṣìíríṣìí tata. Ṣugbọn gbogbo àwọn kòkòrò yòókù tí wọ́n ní ìyẹ́ tí wọ́n sì ní ẹsẹ̀ mẹrin, ìríra ni wọ́n jẹ́ fun yín. “Àwọn ni wọ́n lè sọ yín di aláìmọ́; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú wọn yóo di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Bí ẹnikẹ́ni bá gbé òkú wọn, kí ẹni náà fọ aṣọ rẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Gbogbo ẹranko tí pátákò ẹsẹ̀ wọn bá là, ṣugbọn tí ẹsẹ̀ wọn kò là, tí wọn kì í sì í jẹ àpọ̀jẹ, aláìmọ́ ni wọ́n; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kàn wọ́n di aláìmọ́. Ninu àwọn ẹranko tí wọ́n ń fi ẹsẹ̀ mẹrin rìn, gbogbo àwọn tí wọ́n bá ti ń fi ẹsẹ̀ mẹrẹẹrin rìn tí wọ́n sì ní èékánná jẹ́ aláìmọ́ fun yín; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú wọn yóo di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Bí ẹnikẹ́ni bá gbé òkú wọn, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́; ohun àìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fun yín. “Àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìmọ́ fun yín ninu gbogbo àwọn ohun tí ń rìn lórí ilẹ̀ ni: asín, ati èkúté, ati àwọn oríṣìíríṣìí aláǹgbá ńlá, ọmọọ́lé, ọ̀ni, aláǹgbá, agílíńtí ati alágẹmọ. Wọ́n jẹ́ aláìmọ́ fun yín ninu gbogbo ohun tí ń rìn lórí ilẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú wọn di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Ohunkohun tí òkú wọn bá jábọ́ lé lórí di aláìmọ́, ìbáà jẹ́ ohun èlò igi, tabi aṣọ tabi awọ, tabi àpò, irú ohun èlò yòówù tí ó lè jẹ́, ó níláti di fífọ̀, yóo sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́, lẹ́yìn náà, yóo di mímọ́. Bí èyíkéyìí ninu wọn bá jábọ́ sórí ohun èlò amọ̀, gbogbo ohun tí ó bá wà ninu ohun èlò amọ̀ náà di aláìmọ́, fífọ́ ni kí o fọ́ ohun èlò náà. Ohunkohun tí ó bá jẹ́ jíjẹ tí ó bá wà ninu ìkòkò amọ̀ yìí, tabi tí omi inú rẹ̀ bá ta sí lára, di aláìmọ́, ohunkohun tí ó bá jẹ́ mímu, tí ó wà ninu rẹ̀ náà di aláìmọ́. Ohunkohun tí apákan ninu òkú wọn bá jábọ́ lé lórí di aláìmọ́, kì báà jẹ́ ààrò tabi àdògán, o gbọdọ̀ fọ́ ọ túútúú; wọ́n jẹ́ aláìmọ́, wọ́n sì gbọdọ̀ jẹ́ aláìmọ́ fun yín. Tí ó bá jẹ́ odò, tabi kànga tí ó ní omi ni, wọn kì í ṣe aláìmọ́, ṣugbọn gbogbo nǹkan yòókù tí ó fara kan òkú wọn di aláìmọ́. Bí apákan ninu òkú wọn bá jábọ́ lé orí èso tí eniyan fẹ́ gbìn, èso náà kò di aláìmọ́. Ṣugbọn bí eniyan bá da omi lé èso náà lórí, tí apákan ninu òkú wọn sì já lé èso náà, ó di aláìmọ́ fun yín. “Bí ọ̀kankan ninu àwọn ẹran tí ẹ lè jẹ bá kú, ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan òkú rẹ̀ di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ òkú ẹran náà níláti fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Ẹni tí ó bá ru òkú ẹran náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà. “Ohunkohun tí ń fi àyà fà lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ ìríra, ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹ́. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó bá ń fi àyà wọ́, tabi ohunkohun tí ó bá ń fi ẹsẹ̀ mẹrin rìn tabi ohunkohun tí ó ní ọpọlọpọ ẹsẹ̀, tabi ohunkohun tí ó ń fà lórí ilẹ̀, nítorí ohun ìríra ni wọ́n. Ẹ kò gbọdọ̀ fi ohunkohun tí ń fi àyà fà lórí ilẹ̀ sọ ara yín di ìríra; ẹ kò gbọdọ̀ kó ẹ̀gbin bá ara yín, kí ẹ má baà di aláìmọ́. Nítorí pé, èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì jẹ́ mímọ́, nítorí mímọ́ ni èmi Ọlọrun. Ẹ kò gbọdọ̀ fi ohunkohun tí ń fi àyà fà lórí ilẹ̀ sọ ara yín di aláìmọ́. Nítorí èmi ni OLUWA tí ó ko yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti wá, láti jẹ́ Ọlọrun yín; nítorí náà, ẹ níláti jẹ́ mímọ́, nítorí pé, mímọ́ ni èmi Ọlọrun.” Èyí ni òfin tí ó jẹ mọ́ àwọn ẹranko ati ẹyẹ ati àwọn ẹ̀dá alààyè tí wọn wà ninu omi ati àwọn ẹ̀dá alààyè tí wọ́n ń fi àyà fà lórí ilẹ̀, láti fi ìyàtọ̀ sí ààrin ohun tí ó mọ́, ati ohun tí kò mọ́, ati sí ààrin ẹ̀dá alààyè tí eniyan lè jẹ, ati ẹ̀dá alààyè tí eniyan kò gbọdọ̀ jẹ. OLUWA ní kí Mose sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Bí obinrin kan bá lóyún tí ó sì bí ọmọkunrin, ó di aláìmọ́ fún ọjọ́ meje, gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ aláìmọ́ nígbà tí ó bá ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀. Tí ó bá di ọjọ́ kẹjọ, wọn yóo kọ ilà abẹ́ fún ọmọ náà. Obinrin náà yóo wà ninu ẹ̀jẹ̀ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ fún ọjọ́ mẹtalelọgbọn; kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ kan ohun mímọ́ kan, bẹ́ẹ̀ ni kò sì gbọdọ̀ wá sinu ibi mímọ́, títí tí ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ yóo fi pé. “Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé obinrin ni ó bí, ọ̀sẹ̀ meji ni yóo fi wà ní ipò àìmọ́ bí ó ti jẹ́ aláìmọ́ nígbà tí ó bá ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀; yóo sì wà ninu ẹ̀jẹ̀ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ fún ọjọ́ mẹrindinlaadọrin. “Nígbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ bá pé, kì báà ṣe fún ọmọkunrin tabi fún ọmọbinrin, yóo mú ọ̀dọ́ aguntan ọlọ́dún kan wá sí ọ̀dọ̀ alufaa ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ fún ẹbọ sísun, kí ó sì mú yálà ọmọ ẹyẹlé tabi àdàbà wá, fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Alufaa yóo sì fi rúbọ níwájú OLUWA, yóo ṣe ètùtù fún un; nígbà náà ni yóo di mímọ́ kúrò ninu ìṣàn ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Òfin yìí wà fún obinrin tí ó bá bímọ, kì báà jẹ́ ọmọkunrin ni ó bí tabi ọmọbinrin. “Bí kò bá ní agbára láti mú aguntan wa, kí ó mú àdàbà meji tabi ọmọ ẹyẹlé meji, ọ̀kan fún ẹbọ sísun, ekeji fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, alufaa yóo ṣe ètùtù fún un, yóo sì di mímọ́.” OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé, “Nígbà tí ibìkan bá lé lára eniyan, tabi tí ara eniyan bá wú tí ọ̀gangan ibẹ̀ sì ń dán, tí ó bá jọ ẹ̀tẹ̀ ní ara rẹ̀, kí wọ́n mú olúwarẹ̀ tọ Aaroni, alufaa wá; tabi kí wọ́n mú un wá sí ọ̀dọ̀ ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Aaroni, tí ó jẹ́ alufaa. Kí alufaa náà yẹ ọ̀gangan ibi tí àrùn náà wà lára ẹni náà wò. Bí irun ọ̀gangan ibẹ̀ bá di funfun, tí àrùn náà bá jẹ wọ inú ara ẹni náà lọ, tí ó jìn ju awọ ara rẹ̀ lọ, àrùn ẹ̀tẹ̀ ni. Nígbà tí alufaa bá yẹ̀ ẹ́ wò, kí ó pè é ní aláìmọ́. Ṣugbọn bí ọ̀gangan ibẹ̀ bá funfun tí kò sì jìn ju awọ ara rẹ̀ lọ, tí irun ọ̀gangan ibẹ̀ kò sì di funfun, kí alufaa ti abirùn náà mọ́lé fún ọjọ́ meje. Ní ọjọ́ keje, alufaa náà yóo yẹ abirùn náà wò, bí àrùn náà kò bá tàn káàkiri ara rẹ̀, kí alufaa tún tì í mọ́lé fún ọjọ́ meje sí i. Nígbà tí ó bá tún di ọjọ́ keje, kí alufaa tún yẹ̀ ẹ́ wò. Bí ọ̀gangan ibi tí àrùn náà wà bá bẹ̀rẹ̀ sí wòdú, tí àrùn náà kò sì tàn káàkiri ara rẹ̀, kí alufaa pe ẹni náà ní mímọ́, ara rẹ̀ wú lásán ni; kí ó fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì di mímọ́. Ṣugbọn bí ibi tí ó wú náà bá bẹ̀rẹ̀ sí tàn káàkiri ní ara rẹ̀, lẹ́yìn tí ó fi ara rẹ̀ han alufaa fún ìwẹ̀nùmọ́, kí ó tún pada lọ fi ara han alufaa. Kí alufaa tún yẹ̀ ẹ́ wò, bí ibi tí ó wú náà bá tàn káàkiri sí i ní ara rẹ̀, kí alufaa pè é ní aláìmọ́; àrùn ẹ̀tẹ̀ ni. “Nígbà tí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá mú ẹnìkan, kí wọ́n mú olúwarẹ̀ tọ alufaa lọ. Kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, bí ibìkan bá wú ní ara rẹ̀, tí ó funfun, tí ó sì sọ irun ọ̀gangan ibẹ̀ di funfun, bí ibi tí ó wú yìí bá di egbò, a jẹ́ pé àrùn ẹ̀tẹ̀ gan-an ni ó wà ní ara ẹni náà. Kí alufaa pè é ní aláìmọ́; kí ó má wulẹ̀ tì í mọ́lé, nítorí pé aláìmọ́ ni. Bí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá bo gbogbo ara eniyan láti orí dé àtẹ́lẹsẹ̀ níwọ̀n bí alufaa ti lérò pé ó lè mọ lára eniyan, nígbà náà kí alufaa yẹ olúwarẹ̀ wò, bí àrùn ẹ̀tẹ̀ yìí bá ti bo gbogbo ara rẹ̀ patapata, kí ó pè é ní mímọ́. Bí gbogbo ara rẹ̀ patapata bá ti di funfun, ó di mímọ́. Ṣugbọn gbàrà tí egbò kan bá ti hàn lára rẹ̀, ó di aláìmọ́. Kí alufaa yẹ ojú egbò náà wò, kí ó sì pe abirùn náà ní aláìmọ́, irú egbò yìí jẹ́ aláìmọ́ nítorí pé ẹ̀tẹ̀ ni. Ṣugbọn tí egbò yìí bá jiná, tí ojú rẹ̀ pada di funfun, kí ẹni náà pada tọ alufaa lọ. Kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, bí ojú egbò náà bá ti funfun, nígbà náà ni kí alufaa tó pe abirùn náà ní mímọ́, ó ti di mímọ́. “Bí oówo bá sọ eniyan lára, tí oówo náà sì san. Bí ọ̀gangan ibẹ̀ bá wú, tí ó funfun tabi tí ó pọ́n, kí olúwarẹ̀ lọ fihan alufaa. Kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, bí wúwú tí ó wú yìí bá jìn ju awọ ara rẹ̀ lọ, tí irun rẹ̀ bá sì funfun; kí alufaa pè é ní aláìmọ́; àrùn ẹ̀tẹ̀ ni, ẹ̀tẹ̀ ni ó jẹ jáde gẹ́gẹ́ bí oówo. Ṣugbọn bí alufaa bá yẹ̀ ẹ́ wò, tí irun ọ̀gangan ibẹ̀ kò sì di funfun, tí wúwú tí ó wú kò sì jìn ju awọ ara olúwarẹ̀ lọ, ṣugbọn tí ó wòdú, kí alufaa ti ẹni náà mọ́lé fún ọjọ́ meje. Bí àrùn yìí bá bẹ̀rẹ̀ sí tàn káàkiri lára olúwarẹ̀, kí alufaa pè é ní aláìmọ́; àrùn ẹ̀tẹ̀ ni. Ṣugbọn bí àmì yìí kò bá paradà níbi tí ó wà, tí kò sì tàn káàkiri, àpá oówo lásán ni, kí alufaa pe ẹni náà ní mímọ́. “Tabi bí iná bá jó eniyan lára, tí ó sì di egbò, tí ọ̀gangan ibẹ̀ bá pọ́n tabi tí ó funfun, kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò. Bí irun ọ̀gangan ibẹ̀ bá funfun, tí ó sì jìn ju awọ ara rẹ̀ lọ, àrùn ẹ̀tẹ̀ ni; ẹ̀tẹ̀ ni ó jẹ jáde níbi tí iná ti jó olúwarẹ̀. Kí alufaa pè é ní aláìmọ́; àrùn ẹ̀tẹ̀ ni. Ṣugbọn bí alufaa bá yẹ̀ ẹ́ wò, tí irun ọ̀gangan ibẹ̀ kò funfun, tí kò sì jìn ju awọ ara rẹ̀ lọ, ṣugbọn tí ó wòdú, kí alufaa ti ẹni náà mọ́lé fún ọjọ́ meje. Ní ọjọ́ keje kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, tí àrùn náà bá ti bẹ̀rẹ̀ sí tàn káàkiri ara rẹ̀, kí alufaa pe ẹni náà ní aláìmọ́; àrùn ẹ̀tẹ̀ ni. Bí ibi tí ó wú yìí bá wà bí ó ṣe wà, tí kò sì tàn káàkiri, ṣugbọn tí ó wòdú; àpá iná lásán ni, kí alufaa pè é ní mímọ́. “Bí ọkunrin tabi obinrin bá ní àrùn kan ní orí tabi ní irùngbọ̀n, kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, bí ó bá jìn wọnú ju awọ ara lọ, tí irun ọ̀gangan ibẹ̀ bá pọ́n, tí ó sì fẹ́lẹ́, kí alufaa pè é ní aláìmọ́; àrùn ẹ̀yi ni, tíí ṣe àrùn ẹ̀tẹ̀ irun orí tabi ti irùngbọ̀n. Bí alufaa bá yẹ àrùn ẹ̀yi yìí wò, tí kò bá jìn ju awọ ara lọ, tí irun dúdú kò sì hù jáde ninu rẹ̀, kí alufaa ti ẹni náà mọ́lé fún ọjọ́ meje. Nígbà tí ó bá di ọjọ́ keje, kí alufaa yẹ ẹni náà wò. Bí ẹ̀yi náà kò bá tàn káàkiri, tí irun ibẹ̀ kò sì pọ́n, tí ẹ̀yi náà kò sì jìn ju awọ ara rẹ̀ lọ, kí ó fá irun orí tabi ti àgbọ̀n olúwarẹ̀, ṣugbọn kí ó má fá irun ọ̀gangan ibi tí ẹ̀yi náà wà. Kí alufaa tún ti ẹni náà mọ́lé fún ọjọ́ meje sí i. Nígbà tí ó bá di ọjọ́ keje, kí alufaa yẹ àrùn ẹ̀yi náà wò, tí àrùn náà kò bá tàn káàkiri sí i, tí kò sì jìn ju awọ ara lọ, kí alufaa pè é ní mímọ́, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì di mímọ́. Ṣugbọn bí àrùn ẹ̀yi yìí bá bẹ̀rẹ̀ sí i tàn káàkiri lẹ́yìn ìwẹ̀nùmọ́, kí alufaa tún yẹ̀ ẹ́ wò, bí ẹ̀yi náà bá ti gbilẹ̀ lára rẹ̀, kí alufaa má wulẹ̀ wò bóyá irun rẹ̀ pọ́n tabi kò pọ́n mọ́, aláìmọ́ ni. Ṣugbọn bí ẹ̀yi yìí bá ti dáwọ́ dúró, tí irun dúdú ti bẹ̀rẹ̀ sí hù ní ọ̀gangan ibẹ̀, ẹ̀yi náà ti san, ẹni náà sì ti di mímọ́. Kí alufaa pè é ní mímọ́. “Bí ibìkan lára ọkunrin tabi obinrin bá déédé ṣẹ́ funfun, kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, bí ọ̀gangan ibẹ̀ bá funfun díẹ̀ tí ó dúdú díẹ̀, ara olúwarẹ̀ kàn fín lásán ni, ó mọ́. “Bí irun orí ọkunrin bá re, orí rẹ̀ pá ni, ṣugbọn ó mọ́. Bí irun orí ẹnìkan bá re, ní gbogbo iwájú títí dé ẹ̀bá etí rẹ̀, orí rẹ̀ pá ni; ó mọ́. Ṣugbọn bí ibi tí ó pá ní orí rẹ̀ tabi iwájú rẹ̀ yìí bá lé, tí ó sì pọ́n, ẹ̀tẹ̀ ni ó fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí jẹ jáde níbi tí orí tabi iwájú rẹ̀ ti pá. Kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, tí ibi tí àrùn yìí ti wú ní orí tabi iwájú rẹ̀ bá pọ́n, tí ó sì dàbí ẹ̀tẹ̀ lára rẹ̀, adẹ́tẹ̀ ni ọkunrin náà, kò mọ́; alufaa sì gbọdọ̀ pè é ní aláìmọ́. Orí rẹ̀ ni àrùn yìí wà. “Ẹni tí ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀ yìí gbọdọ̀ wọ aṣọ tí ó ya, kí ó fi apá kan irun orí rẹ̀ sílẹ̀ játijàti, kí ó bo ètè rẹ̀ òkè, kí ó sì máa ké pé, ‘Aláìmọ́! Aláìmọ́!’ Yóo jẹ́ aláìmọ́, níwọ̀n ìgbà tí àrùn yìí bá wà lára rẹ̀. Ó jẹ́ aláìmọ́; òun nìkan ni yóo sì máa dá gbé lẹ́yìn ibùdó. “Nígbà tí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá wà lára aṣọ kan, kì báà jẹ́ pé òwú tabi irun tí wọ́n fi hun aṣọ náà, tabi lára aṣọkáṣọ, kì báà jẹ́ olówùú tabi onírun, tabi lára awọ, tabi lára ohunkohun tí a fi awọ ṣe. Bí ibi tí àrùn yìí wà bá bẹ̀rẹ̀ sí í pọ́n tabi, kí ó ní àwọ̀ bíi ti ewéko, kì báà jẹ́ aṣọ olówùú, tabi ti onírun, tabi kí ó jẹ́ awọ tabi ohunkohun tí a fi awọ ṣe, àrùn ẹ̀tẹ̀ ni; dandan ni kí wọ́n fihan alufaa. Kí alufaa yẹ àrùn náà wò, kí ó sì ti aṣọ tí àrùn náà ràn mọ́ mọ́lé fún ọjọ́ meje. Kí ó yẹ àrùn ara aṣọ náà wò ní ọjọ́ keje, bí ó bá ti tàn káàkiri lára aṣọ tabi awọ náà, ohun yòówù tí wọ́n lè máa fi aṣọ náà ṣe, irú ẹ̀tẹ̀ tí ó máa ń ràn káàkiri ni; kò mọ́. Kí alufaa jó aṣọ náà, ibi yòówù tí àrùn náà lè wà lára rẹ̀, kì báà jẹ́ aṣọ onírun tabi olówùú, tabi ohunkohun tí wọ́n fi awọ ṣe; nítorí pé irú àrùn tí ó máa ń ràn káàkiri ara ni; jíjó ni kí wọ́n jó o níná. “Bí alufaa bá yẹ̀ ẹ́ wò, tí àrùn náà kò bá ràn káàkiri lára aṣọ náà tabi ohun èlò awọ náà, alufaa yóo pàṣẹ pé kí wọ́n fọ ohun èlò tí àrùn wà lára rẹ̀ yìí, yóo sì tún tì í mọ́lé fún ọjọ́ meje sí i. Alufaa yóo tún yẹ ohun èlò tí àrùn náà ràn mọ́ wò lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fọ̀ ọ́. Bí ọ̀gangan ibi tí àrùn yìí ràn mọ́ kò bá mọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tàn káàkiri sí i; sibẹ kò mọ́; jíjó ni ó níláti jó o níná, kì báà jẹ́ iwájú, tabi ẹ̀yìn aṣọ tabi awọ náà ni àrùn ràn mọ́. Ṣugbọn nígbà tí alufaa bá yẹ̀ ẹ́ wò, tí ó sì rí i pé àrùn náà ti wòdú lẹ́yìn tí a fọ aṣọ náà, kí ó gé ọ̀gangan ibẹ̀ kúrò lára ẹ̀wù, tabi aṣọ, tabi awọ náà. Bí ó bá tún jẹ jáde lára ẹ̀wù, tabi lára aṣọ, tabi ohun èlò aláwọ náà, a jẹ́ pé ó bẹ̀rẹ̀ sí tàn káàkiri nìyí, jíjó ni kí ó jó ohun èlò náà níná. Ṣugbọn ẹ̀wù tabi aṣọ, tabi ohun èlò awọ, tí àrùn yìí bá lọ kúrò lára rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti fọ̀ ọ́, kí olúwarẹ̀ tún un fọ̀ lẹẹkeji, yóo sì di mímọ́.” Ó jẹ́ òfin tí ó jẹmọ́ àrùn ẹ̀tẹ̀ tí ó bá wà lára ẹ̀wù tabi aṣọ, láti fi mọ̀ bóyá ó mọ́ tabi kò mọ́, kì báà jẹ́ aṣọ onírun tabi olówùú, tabi ohun èlò aláwọ. OLUWA sọ fún Mose pé, “Òfin tí ó jẹmọ́ ti ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ adẹ́tẹ̀ nìyí: kí wọ́n mú adẹ́tẹ̀ náà wá sí ọ̀dọ̀ alufaa. Kí alufaa jáde kúrò ninu àgọ́, kí ó sì yẹ̀ ẹ́ wò bí àrùn ẹ̀tẹ̀ náà bá ti san. Alufaa yóo pàṣẹ pé kí wọ́n bá ẹni tí wọ́n fẹ́ ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún mú ẹyẹ mímọ́ meji wá ati igi kedari, pẹlu aṣọ pupa tẹ́ẹ́rẹ́ kan, ati ewé hisopu. Alufaa yóo pàṣẹ pé kí wọ́n pa ọ̀kan ninu àwọn ẹyẹ náà sinu ìkòkò amọ̀, lórí odò tí ń ṣàn. Yóo mú ẹyẹ tí ó wà láàyè ati igi kedari, ati aṣọ pupa tẹ́ẹ́rẹ́, ati ewé hisopu, yóo pa wọ́n pọ̀, yóo sì tì wọ́n bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tí wọ́n pa lórí odò tí ń ṣàn. Yóo wọ́n ọn sí ara ẹni tí wọ́n fẹ́ wẹ̀ mọ́ kúrò ninu àrùn ẹ̀tẹ̀ náà nígbà meje. Lẹ́yìn náà alufaa yóo pè é ní mímọ́, yóo sì jẹ́ kí ẹyẹ keji tí ó wà láàyè, fò wọ igbó lọ. Kí ẹni tí wọ́n fẹ́ wẹ̀ mọ́ náà fọ aṣọ rẹ̀, kí ó fá irun rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo sì di mímọ́. Lẹ́yìn náà, yóo wá sí ibùdó, ṣugbọn ẹ̀yìn àgọ́ rẹ̀ ni yóo máa gbé fún ọjọ́ meje. Ní ọjọ́ keje yóo fá irun orí rẹ̀, ati irùngbọ̀n rẹ̀, ati irun ìpéǹpéjú rẹ̀ ati gbogbo irun ara rẹ̀ patapata, yóo fọ gbogbo aṣọ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, yóo wẹ̀, yóo sì di mímọ́. “Ní ọjọ́ kẹjọ, yóo mú ọ̀dọ́ àgbò meji tí kò lábàwọ́n, ati ọ̀dọ́ abo aguntan ọlọ́dún kan tí kò lábàwọ́n, ati ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, tí a fi òróró pò ati ìwọ̀n ìgò òróró kan fún ẹbọ ohun jíjẹ. Alufaa tí ó ṣe ètò ìwẹ̀nùmọ́ ẹni náà yóo mú adẹ́tẹ̀ náà ati àwọn nǹkan ìwẹ̀nùmọ́ wá siwaju OLUWA lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. Lẹ́yìn náà, yóo mú ọ̀kan ninu àwọn ọ̀dọ́ àgbò náà, yóo fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, pẹlu ìwọ̀n ìgò òróró kan, yóo fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA. Alufaa náà yóo pa àgbò náà níbi tí wọ́n ti máa ń pa ẹran fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ti ẹbọ sísun ninu ibi mímọ́, nítorí pé ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi jẹ́ ti alufaa, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀; ohun mímọ́ patapata ni. Alufaa yóo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ẹran ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi yìí, yóo fi kan ṣóńṣó etí ọ̀tún, ati àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún ati àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún ẹni tí wọ́n fẹ́ wẹ̀ mọ́. Alufaa yóo mú ninu ìwọ̀n ìgò òróró náà, yóo dà á sí àtẹ́lẹwọ́ òsì rẹ̀. Yóo ti ìka ọ̀tún rẹ̀ bọ òróró tí ó wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀, yóo sì fi ìka rẹ̀ wọ́n òróró náà níwájú OLUWA ní ìgbà meje. Alufaa yóo mú ninu òróró tí ó kù ní ọwọ́ òsì rẹ̀, yóo fi kan ṣóńṣó etí ọ̀tún ẹni tí wọ́n fẹ́ sọ di mímọ́, ati àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ati àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀, tí ó ti kọ́ fi ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi kàn. Alufaa yóo fi òróró tí ó kù ní ọwọ́ rẹ̀ ra orí ẹni tí wọ́n fẹ́ sọ di mímọ́. Lẹ́yìn náà, yóo ṣe ètùtù fún un níwájú OLUWA. “Alufaa yóo rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún ẹni tí wọ́n fẹ́ sọ di mímọ́, lẹ́yìn náà, yóo pa ẹran ẹbọ sísun náà. Alufaa yóo rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ lórí pẹpẹ. Bẹ́ẹ̀ ni alufaa yóo ṣe ṣe ètùtù fún un, tí yóo sì di mímọ́. “Ṣugbọn bí adẹ́tẹ̀ náà bá talaka tóbẹ́ẹ̀ tí apá rẹ̀ kò ká àwọn nǹkan tí a kà sílẹ̀ wọnyi, ó lè mú àgbò kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, tí alufaa yóo fì, láti fi ṣe ètùtù fún un. Kí ó sì tún mú ìdámẹ́wàá ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun kan tí ó kúnná dáradára, tí wọ́n fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ, pẹlu ìwọ̀n ìgò òróró kan, ati àdàbà meji tabi ọmọ ẹyẹlé meji, èyíkéyìí tí apá rẹ̀ bá ká. Wọn yóo fi ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, wọn yóo sì fi ekeji rú ẹbọ sísun. Ní ọjọ́ kẹjọ, yóo kó wọn tọ alufaa wá ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, níwájú OLUWA fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀. Alufaa yóo mú àgbò ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi ati ìwọ̀n ìgò òróró náà, yóo fì wọ́n bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA. Yóo pa àgbò ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, yóo sì mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, yóo fi kan ṣóńṣó etí ọ̀tún ẹni tí wọ́n fẹ́ sọ di mímọ́ ati àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ati àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀. Alufaa yóo bu díẹ̀ ninu òróró náà sí àtẹ́lẹwọ́ òsì rẹ̀, yóo ti ìka bọ inú òróró tí ó wà ní ọwọ́ òsì yìí, yóo sì wọ́n ọn sílẹ̀ níwájú OLUWA nígbà meje. Alufaa yóo mú díẹ̀ ninu òróró tí ó wà ni ọwọ́ òsì rẹ̀, yóo fi kan ṣóńṣó etí ọ̀tún ẹni tí wọ́n fẹ́ sọ di mímọ́ ati àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ati àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀ tí ó ti kọ́ fi ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi kàn. Alufaa yóo mú òróró tí ó kù ní ọwọ́ rẹ̀ yóo sì fi ra orí ẹni tí wọ́n fẹ́ wẹ̀ mọ́, láti fi ṣe ètùtù fún un níwájú OLUWA. Yóo fi èyí tí apá rẹ̀ bá ká rúbọ: yálà àdàbà tabi ẹyẹlé; ọ̀kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ekeji fún ẹbọ sísun, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ. Alufaa yóo sì ṣe ètùtù fún un níwájú OLUWA. Èyí ni òfin tí ó jẹmọ́ ti ẹni tí ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀, ṣugbọn tí apá rẹ̀ kò ká àwọn ohun ìrúbọ fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀.” OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé, “Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ Kenaani tí n óo fun yín, tí yóo jẹ́ ohun ìní yín, bí mo bá fi àrùn ẹ̀tẹ̀ sí ilé kan ninu ilẹ̀ yín. Ẹni tí ó ni ilé náà yóo wá sọ fún alufaa pé, ‘Ó dàbí ẹni pé àrùn kan wà ní ilé mi.’ Kí alufaa pàṣẹ pé kí wọn kó gbogbo ohun tí ó wà ninu ilé náà jáde, kí ó tó lọ yẹ àrùn náà wò; kí ó má baà pe gbogbo ohun tí ó wà ninu ilé náà ní aláìmọ́; lẹ́yìn náà, kí alufaa lọ wo ilé náà. Kí ó yẹ àrùn náà wò, bí ó bá jẹ́ pé lára ògiri ilé ni àrùn yìí wà, tí ibi tí ó wà lára ògiri náà dàbí àwọ̀ ewéko tabi tí ó pọ́n, tí ọ̀gangan ibẹ̀ sì jìn ju ara ògiri lọ. Kí alufaa jáde kúrò ninu ilé náà, kí ó lọ síbi ìlẹ̀kùn, kí ó ti ìlẹ̀kùn ilé náà fún ọjọ́ meje. Alufaa yóo pada wá ní ọjọ́ keje láti yẹ ilé náà wò. Bí àrùn bá ti tàn káàkiri lára ògiri ilé náà, yóo pàṣẹ pé kí wọn yọ àwọn òkúta tí àrùn wà lára wọn, kí wọ́n kó wọn sí ibìkan tí kò mọ́ lẹ́yìn ìlú. Yóo pàṣẹ pé kí wọ́n ha gbogbo ògiri ilé náà yípo, kí wọ́n kó gbogbo ohun tí wọ́n fi rẹ́ ilé, tí wọ́n ha kúrò, kí wọ́n dà á sí ibìkan tí kò mọ́ lẹ́yìn ìlú. Wọn yóo wá wá àwọn òkúta mìíràn, wọn yóo fi dípò àwọn tí wọ́n yọ kúrò, yóo sì fi ohun ìrẹ́lé mìíràn tún ilé náà rẹ́. “Bí àrùn yìí bá tún jẹ jáde lára ilé náà, lẹ́yìn tí ó ti yọ àwọn òkúta àkọ́kọ́ jáde, tí ó ti ha ògiri ilé náà, tí ó sì ti tún un rẹ́, alufaa yóo lọ yẹ ilé náà wò. Bí àrùn náà bá tàn káàkiri lára ògiri ilé náà, a jẹ́ pé àrùn ẹ̀tẹ̀ tí í máa ń tàn káàkiri ni; ilé náà kò mọ́. Wọ́n gbọdọ̀ wó o lulẹ̀ ni, kí wọ́n ru gbogbo òkúta rẹ̀ ati igi tí wọ́n fi kọ́ ọ ati ohun ìrẹ́lé tí wọ́n fi rẹ́ ẹ jáde kúrò láàrin ìlú, lọ sí ibi tí kò mọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ ilé náà lẹ́yìn tí alufaa ti tì í pa, yóo di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sùn ninu ilé náà tabi tí ó bá jẹun ninu rẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀. “Ṣugbọn bí alufaa bá wá yẹ ilé náà wò, tí àrùn náà kò bá tàn káàkiri lára ògiri rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti tún un rẹ́, alufaa yóo pe ilé náà ní mímọ́, nítorí àrùn náà ti san. Nígbà tí alufaa bá fẹ́ sọ ilé náà di mímọ́, yóo mú ẹyẹ kéékèèké meji ati igi kedari ati aṣọ pupa tẹ́ẹ́rẹ́ kan, ati ewé hisopu, yóo pa ọ̀kan ninu àwọn ẹyẹ náà sinu ìkòkò amọ̀ lórí odò tí ń ṣàn, yóo mú igi Kedari ati ewé hisopu ati aṣọ pupa tẹ́ẹ́rẹ́ náà, ati ẹyẹ keji, tí ó wà láàyè, yóo tì wọ́n bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tí ó pa lórí odò tí ń ṣàn, yóo wọ́n ọn sára ilé náà nígbà meje. Bẹ́ẹ̀ ni yóo ṣe fi ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ náà ati omi tí ń ṣàn, ati ẹyẹ tí ó wà láàyè, ati igi Kedari, ati ewé hisopu, ati aṣọ pupa tẹ́ẹ́rẹ́ náà sọ ilé náà di mímọ́ pada. Yóo ju ẹyẹ náà sílẹ̀ kí ó lè fò jáde kúrò ninu ìlú, lọ sinu pápá, yóo fi ṣe ètùtù fún ìwẹ̀nùmọ́ ilé náà, ilé náà yóo sì di mímọ́.” Àwọn òfin tí a ti kà sílẹ̀ wọnyi ni òfin tí ó jẹmọ́ oríṣìíríṣìí àrùn ẹ̀tẹ̀ ati ti ẹ̀yi ara; ati ti àrùn ẹ̀tẹ̀ lára aṣọ tabi lára ilé, ati ti oríṣìíríṣìí egbò, ati oówo, ati ti ara wúwú, tabi ti aṣọ tabi ilé tí àrùn ẹ̀tẹ̀ bò, láti fi hàn bí ó bá jẹ́ mímọ́, tabi kò jẹ́ mímọ́. Àwọn ni òfin tí ó jẹmọ́ àrùn ẹ̀tẹ̀. OLUWA ní kí Mose ati Aaroni sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, “Nígbà tí nǹkan bá dà jáde lára ọkunrin, nǹkan tí ó jáde lára rẹ̀ yìí jẹ́ aláìmọ́. Èyí sì ni òfin tí ó jẹmọ́ àìmọ́ rẹ̀, nítorí nǹkan tí ó ti ara rẹ̀ jáde; kì báà jẹ́ pé ó ń dà lọ́wọ́ lọ́wọ́, tabi ó ti dà tán, nǹkan tí ó dà yìí jẹ́ àìmọ́ lára rẹ̀. Ibùsùn tí ẹni náà bá dùbúlẹ̀ lé lórí di aláìmọ́, ohunkohun tí ó bá sì fi jókòó di aláìmọ́ pẹlu. Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan ibùsùn rẹ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jókòó lórí ohunkohun tí ẹni tí nǹkan bá dà lára rẹ̀ bá fi jókòó, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀; yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan ẹni náà, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Bí ẹnikẹ́ni tí nǹkan dà lára rẹ̀ bá tutọ́ sí ara ẹni tí ó mọ́, kí ẹni náà fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Gàárì ẹṣin tí ẹni tí nǹkan bá dà lára rẹ̀ bá fi gun ẹṣin di aláìmọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi ọwọ́ kan ohunkohun, ninu ohun tí ó fi jókòó di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ru èyíkéyìí ninu àwọn nǹkan tí ẹni náà fi jókòó, fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀; olúwarẹ̀ yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Ẹni tí nǹkan ọkunrin dà lára rẹ̀ yìí gbọdọ̀ fọ ọwọ́ rẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ẹni náà bá fi ọwọ́ kàn, kí ó tó fọ ọwọ́ rẹ̀, olúwarẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀ yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Kí wọ́n fọ́ kòkò tí ẹni tí nǹkan dà lára rẹ̀ yìí bá fi ọwọ́ kàn. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ohun èlò onígi tí ó bá fọwọ́ kàn, wọ́n gbọdọ̀ fọ̀ wọn. “Nígbà tí wọ́n bá sọ ẹni tí nǹkan dà lára rẹ̀ yìí di mímọ́ kúrò ninu ohun tí ó dà lára rẹ̀, kí ó ka ọjọ́ meje fún ìwẹ̀nùmọ́, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀ ninu odò tí ó ń ṣàn; yóo sì di mímọ́. Nígbà tí ó bá di ọjọ́ kẹjọ, kí ó mú àdàbà meji, tabi ọmọ ẹyẹlé meji, kí ó wá siwaju OLUWA lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, kí ó sì kó wọn fún alufaa. Alufaa yóo fi wọ́n rúbọ: yóo fi ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, yóo sì fi ekeji rú ẹbọ sísun. Yóo ṣe ètùtù fún ìwẹ̀nùmọ́ ọkunrin náà, níwájú OLUWA. “Kí ọkunrin tí nǹkan ọkunrin rẹ̀ bá dà sí lára, kí ó wẹ gbogbo ara rẹ̀ láti òkè dé ilẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Gbogbo aṣọ ati awọ tí nǹkan ọkunrin náà bá dà sí gbọdọ̀ jẹ́ fífọ̀, kí ó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Bí ọkunrin bá bá obinrin lòpọ̀, tí nǹkan ọkunrin sì jáde lára rẹ̀, kí àwọn mejeeji wẹ̀, kí wọ́n sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. “Nígbà tí obinrin bá ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀, kí ó wà ní ipò àìmọ́ fún ọjọ́ meje. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi ara kàn án jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Ohunkohun tí ó bá dùbúlẹ̀ lé lórí, tabi tí ó jókòó lé lórí ní gbogbo àkókò àìmọ́ rẹ̀ yóo di aláìmọ́. Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan ibùsùn rẹ̀, fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀; yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan ohunkohun tí ó fi jókòó, fọ aṣọ rẹ̀, kí ó wẹ̀; yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Kì báà jẹ́ ibùsùn rẹ̀ ni, tabi ohunkohun tí ó fi jókòó ni eniyan bá fi ara kàn, ẹni náà yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Bí ọkunrin kan bá bá a lòpọ̀ nígbà tí ó bá ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀, ọkunrin náà yóo jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ meje, ibùsùn tí ọkunrin náà bá sì dùbúlẹ̀ lé lórí yóo jẹ́ aláìmọ́. “Bí ẹ̀jẹ̀ bá ń dà lára obinrin fún ọpọlọpọ ọjọ́, tí kì í sì í ṣe àkókò nǹkan oṣù rẹ̀, tabi tí nǹkan oṣù rẹ̀ bá dà kọjá iye ọjọ́ tí ó yẹ kí ó dà, ó jẹ́ aláìmọ́ ní gbogbo àkókò tí ẹ̀jẹ̀ ń dà lára rẹ̀. Yóo jẹ́ aláìmọ́ bí ìgbà tí ó ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀. Ibùsùn tí ó bá dùbúlẹ̀ lé lórí, ní gbogbo ọjọ́ tí nǹkan yìí bá fi ń dà lára rẹ̀ yóo jẹ́ aláìmọ́; ohunkohun tí ó bá sì fi jókòó di aláìmọ́ gẹ́gẹ́ bíi ti àkókò tí ó ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi ara kan ibùsùn tabi ìjókòó rẹ̀, yóo di aláìmọ́; kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Ṣugbọn nígbà tí ẹ̀jẹ̀ náà bá dá, kí ó ka ọjọ́ meje lẹ́yìn ọjọ́ náà; lẹ́yìn náà, ó di mímọ́. Nígbà tí ó bá di ọjọ́ kẹjọ, kí ó mú àdàbà meji, tabi ọmọ ẹyẹlé meji tọ alufaa lọ ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. Kí alufaa fi ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, kí ó sì fi ekeji rú ẹbọ sísun, kí ó ṣe ètùtù fún un níwájú OLUWA nítorí ohun àìmọ́ tí ó jáde lára rẹ̀. “Bẹ́ẹ̀ ni o óo ṣe ya àwọn eniyan Israẹli kúrò lára àìmọ́ wọn, kí wọ́n má baà sọ ibi mímọ́ tí ó wà láàrin wọn di aláìmọ́, kí wọ́n sì kú.” Òfin yìí ni ó jẹmọ́ ti ọkunrin tí nǹkankan tabi nǹkan ọkunrin bá dà lára rẹ̀, tí ó sì ti ipa bẹ́ẹ̀ di aláìmọ́; ati obinrin tí ó ṣe nǹkan oṣù rẹ̀ tabi tí nǹkan oṣù di àìsàn sí lára; ẹnikẹ́ni tí nǹkan bá sá ti ń dà lára rẹ̀, kì báà jẹ́ ọkunrin tabi obinrin, ati ọkunrin tí ó bá bá obinrin tí ó jẹ́ aláìmọ́ lòpọ̀. Lẹ́yìn tí meji ninu àwọn ọmọ Aaroni kú, nígbà tí wọ́n fi iná tí kò mọ́ rúbọ sí OLUWA, OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Sọ fún Aaroni arakunrin rẹ pé kí ó má ṣe máa wọ ibi mímọ́ jùlọ, tí ó wà lẹ́yìn aṣọ títa, níwájú ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí àpótí ẹ̀rí nígbà gbogbo, kí ó má baà kú; nítorí pé n óo fi ara hàn ninu ìkùukùu, lórí ìtẹ́ àánú. Ṣugbọn ohun tí yóo ṣe, nígbà tí yóo bá wọ ibi mímọ́ náà nìyí: kí ó mú ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan lọ́wọ́ fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati àgbò kan fún ẹbọ sísun. “Kí ó kọ́kọ́ wẹ̀, lẹ́yìn náà, kí ó wọ àwọn aṣọ mímọ́ nnì: ẹ̀wù funfun mímọ́, pẹlu ṣòkòtò funfun, kí ó fi ọ̀já funfun di àmùrè, kí ó sì dé fìlà funfun. “Yóo gba òbúkọ meji lọ́wọ́ ìjọ eniyan Israẹli fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati àgbò kan fún ẹbọ sísun. Aaroni yóo fi ọ̀dọ́ mààlúù kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀, yóo sì ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ ati ilé rẹ̀. Lẹ́yìn náà yóo mú àwọn ewúrẹ́ mejeeji, yóo fà wọ́n kalẹ̀ níwájú OLUWA, ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. Lẹ́yìn náà, yóo ṣẹ́ gègé lórí àwọn ewúrẹ́ mejeeji, gègé kan fún OLUWA, ekeji fún Asaseli. Aaroni yóo fa ẹran tí gègé OLUWA bá mú kalẹ̀ níwájú OLUWA, yóo sì fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ṣugbọn láàyè ni yóo fa ẹran tí gègé Asaseli bá mú kalẹ̀ níwájú OLUWA, yóo ṣe ètùtù lórí rẹ̀, yóo sì tú u sílẹ̀, kí ó sá tọ Asaseli lọ ninu aṣálẹ̀. “Aaroni yóo fa akọ mààlúù kan kalẹ̀ tí yóo fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀, yóo sì ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ ati ilé rẹ̀; yóo pa akọ mààlúù náà fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀. Lẹ́yìn náà, yóo mú ẹ̀yinná láti orí pẹpẹ tí ó wà níwájú OLUWA sinu àwo turari, yóo sì bu turari olóòórùn dídùn tí wọ́n gún, ẹ̀kúnwọ́ meji, yóo sì gbé e lọ sinu ibi tí aṣọ ìbòjú wà. Yóo da turari náà sórí iná níwájú OLUWA, kí èéfín turari náà lè bo ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí àpótí ẹ̀rí, kí Aaroni má baà kú. Yóo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù náà, yóo fi ìka wọ́n ọn siwaju ìbòrí ìtẹ́ àánú. Bákan náà, yóo fi ìka wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà siwaju Àpótí Ẹ̀rí nígbà meje. “Lẹ́yìn náà yóo pa ewúrẹ́ ìrúbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn eniyan Israẹli, yóo sì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ sinu ibi tí aṣọ ìbòjú wà, yóo sì ṣe é bí ó ti ṣe ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù, yóo wọ́n ọn siwaju ìbòrí ìtẹ́ àánú, yóo sì tún wọ́n ọn siwaju Àpótí Ẹ̀rí. Bẹ́ẹ̀ ni yóo ti ṣe ètùtù fún ibi mímọ́ náà, nítorí àìmọ́ àwọn eniyan Israẹli, ati nítorí ìrékọjá ati gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ gan-an ni yóo sì ṣe sí Àgọ́ Àjọ tí ó wà láàrin wọn, nítorí àìmọ́ wọn. Kò ní sí ẹnikẹ́ni ninu Àgọ́ Àjọ nígbà tí ó bá wọlé lọ láti ṣe ètùtù ninu ibi mímọ́ náà, títí tí yóo fi jáde, lẹ́yìn tí ó bá ti ṣe ètùtù fún ara rẹ̀, ati ilé rẹ̀, ati fún gbogbo ìjọ eniyan Israẹli. Lẹ́yìn náà, yóo jáde lọ sí ibi pẹpẹ tí ó wà níwájú OLUWA, yóo sì ṣe ètùtù fún un. Yóo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù náà ati ti ewúrẹ́ náà, yóo sì fi ra àwọn ìwo pẹpẹ náà yípo. Yóo sì fi ìka wọ́n díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ náà sí ara pẹpẹ nígbà meje, yóo sọ ọ́ di mímọ́, yóo sì yà á sí mímọ́ kúrò ninu àìmọ́ àwọn eniyan Israẹli. “Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti parí ṣíṣe ètùtù fún ibi mímọ́ náà, ati fún Àgọ́ Àjọ náà, ati pẹpẹ náà, yóo fa ààyè ewúrẹ́ náà kalẹ̀. Yóo gbé ọwọ́ rẹ̀ mejeeji lé e lórí, yóo jẹ́wọ́ gbogbo àìṣedéédé ati ìrékọjá ati ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli lórí rẹ̀, yóo sì kó wọn lé e lórí, yóo fà á lé ẹnìkan tí ó ti múra sílẹ̀ lọ́wọ́, láti fà á lọ sinu aṣálẹ̀. Òbúkọ náà yóo sì fi orí rẹ̀ ru gbogbo àìṣedéédé wọn, títí tí ẹni náà yóo fi fà á dé ibi tí eniyan kì í gbé, ibẹ̀ ni yóo ti sọ ọ́ sílẹ̀ kí ó lè wọ inú aṣálẹ̀ lọ. “Aaroni yóo pada wá sinu Àgọ́ Àjọ, yóo bọ́ àwọn aṣọ funfun tí ó wọ̀ kí ó tó wọ inú ibi mímọ́ lọ, yóo sì fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀. Yóo wẹ̀ ní ibi mímọ́, yóo kó àwọn aṣọ tirẹ̀ wọ̀, yóo sì jáde. Lẹ́yìn náà yóo rú ẹbọ sísun tirẹ̀ ati ẹbọ sísun ti àwọn eniyan náà, yóo sì ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ ati fún àwọn eniyan náà. Yóo sun ọ̀rá ẹran ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ lórí pẹpẹ náà. Ẹni tí ó fa ewúrẹ́ náà tọ Asaseli lọ ninu aṣálẹ̀ yóo fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì wẹ̀, lẹ́yìn náà, ó lè wọ ibùdó. Lẹ́yìn náà, wọn yóo gbé òkú akọ mààlúù ati ti òbúkọ tí wọ́n fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ẹ̀jẹ̀ wọn tí wọ́n gbé wọ ibi mímọ́ lọ láti fi ṣe ètùtù, wọn yóo rù wọ́n jáde kúrò ní ibùdó, wọn yóo sì dáná sun ati awọ, ati ara ẹran ati nǹkan inú wọn. Ẹni tí ó bá lọ sun wọ́n, yóo fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì wẹ̀, lẹ́yìn náà, ó lè wọ ibùdó wá. “Kí ó jẹ́ ìlànà fun yín títí lae pé, ní ọjọ́ kẹwaa oṣù keje, ati onílé ati àlejò yín, ẹ gbọdọ̀ gbààwẹ̀, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. Nítorí pé, ní ọjọ́ náà ni wọn yóo máa ṣe ètùtù fun yín, tí yóo sọ yín di mímọ́ kúrò ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ lè jẹ́ mímọ́ níwájú OLUWA. Ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀ ni ó jẹ́ fun yín, ẹ sì gbọdọ̀ gbààwẹ̀; ìlànà ni èyí jẹ́ fun yín títí lae. Alufaa tí wọ́n bá ta òróró sí lórí, tí wọ́n sì yà sí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí alufaa àgbà ní ipò baba rẹ̀ ni kí ó máa ṣe ètùtù, kí ó sì máa wọ aṣọ mímọ́ náà. Yóo ṣe ètùtù fún Àgọ́ mímọ́ náà, ati Àgọ́ Àjọ, ati pẹpẹ náà, kí ó sì ṣe ètùtù fún àwọn alufaa pẹlu ati ìjọ eniyan náà. Èyí yóo jẹ́ ìlànà ayérayé fun yín, kí wọ́n lè máa ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli ní ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” Mose sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún un. OLUWA sọ fún Mose pé kí ó sọ fún Aaroni, ati àwọn ọmọkunrin rẹ̀, ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ohun tí OLUWA paláṣẹ nìyí: Bí ẹnìkan ninu àwọn ọmọ Israẹli bá pa akọ mààlúù, tabi ọ̀dọ́ aguntan, tabi ewúrẹ́ kan ní ibùdó, tabi lẹ́yìn ibùdó, tí kò bá mú un wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ láti fi ṣe ẹ̀bùn fún OLUWA níwájú Àgọ́ mímọ́ rẹ̀, olúwarẹ̀ yóo jẹ̀bi ìtàjẹ̀sílẹ̀, ó ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, a óo sì yọ ọ́ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀. OLUWA pa àṣẹ yìí kí àwọn ọmọ Israẹli lè máa mú ẹran ìrúbọ tí wọ́n bá pa ninu pápá wá fún OLUWA, kí wọn mú un tọ alufaa wá lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, kí wọn sì pa á láti fi rú ẹbọ alaafia sí OLUWA. Alufaa yóo sì máa wọ́n ẹ̀jẹ̀ wọn sí ara pẹpẹ OLUWA lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, yóo sì sun ọ̀rá wọn bí ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA. Kí àwọn ọmọ Israẹli má baà tún máa fi ẹran wọn rúbọ sí oriṣa bí wọ́n ti ń ṣe rí. Òfin yìí wà fún arọmọdọmọ wọn títí lae. “Bákan náà, ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli tabi àlejò tí ń ṣe àtìpó láàrin wọn, tí ó bá rú ẹbọ sísun tabi ẹbọ mìíràn, tí kò bá mú ẹran tí yóo fi rú ẹbọ náà wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ láti fi rúbọ sí OLUWA, a óo yọ ẹni náà kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀. “Bí ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli tabi àlejò tí ń ṣe àtìpó láàrin wọn bá jẹ ẹ̀jẹ̀, èmi OLUWA yóo bínú sí olúwarẹ̀, n óo sì yọ ọ́ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀. Nítorí pé, ninu ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí ohun alààyè gbogbo wà; mo sì ti fun yín, pé kí ẹ máa ta á sórí pẹpẹ, kí ẹ máa fi ṣe ètùtù fún ẹ̀mí yín; nítorí pé ẹ̀jẹ̀ níí ṣe ètùtù, nítorí ẹ̀mí tí ó wà ninu rẹ̀. Nítorí rẹ̀ ni mo fi sọ fún ẹ̀yin ọmọ Israẹli pé, ẹnikẹ́ni ninu yín kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni àlejò tí ń ṣe àtìpó láàrin yín kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀. “Ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli, tabi àwọn àlejò tí ń ṣe àtìpó láàrin wọn tí ó bá lọ ṣe ọdẹ tí ó sì pa ẹran tabi ẹyẹ tí eniyan lè jẹ, ó níláti ro gbogbo ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ kí ó sì wa erùpẹ̀ bò ó. Nítorí pé, ninu ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí gbogbo ohun alààyè wà, nítorí náà ni mo fi sọ fún ẹ̀yin ọmọ Israẹli pé, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ẹ̀dá alààyè kankan, nítorí pé, ninu ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí ẹ̀dá alààyè gbogbo wà, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́, a óo yọ ọ́ kúrò. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì jẹ ohunkohun tí ó kú fúnra rẹ̀, tabi tí ẹranko burúkú fà ya, kí ẹni náà fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́, lẹ́yìn ìgbà náà ni yóo tó pada di mímọ́. Ṣugbọn, tí kò bá fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.” OLUWA ní kí Mose, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe bí wọ́n ti ń ṣe ní ilẹ̀ Ijipti, níbi tí ẹ ti gbé rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ ṣe bí wọ́n ti ń ṣe ní ilẹ̀ Kenaani níbi tí mò ń ko yín lọ. Ẹ kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ìlànà wọn. Àwọn òfin mi ni ẹ gbọdọ̀ pamọ́, àwọn ìlànà mi sì ni ẹ gbọdọ̀ máa tẹ̀lé, tí ẹ sì gbọdọ̀ máa tọ̀. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín. Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ máa tẹ̀lé ìlànà mi kí ẹ sì máa pa àwọn òfin mi mọ́. Ẹni tí ó bá ń pa wọ́n mọ́ yóo wà láàyè. Èmi ni OLUWA. “Ẹnikẹ́ni ninu yín kò gbọdọ̀ tọ ìbátan rẹ̀ lọ láti bá a lòpọ̀. Èmi ni OLUWA. Ẹnikẹ́ni ninu yín kò gbọdọ̀ bá ìyá rẹ̀ lòpọ̀, nítorí pé, bí ẹni ń tú baba ẹni síhòòhò ni, ìyá rẹ ni, o kò gbọdọ̀ tú ìyá rẹ síhòòhò. O kò gbọdọ̀ bá aya baba rẹ lòpọ̀ nítorí pé bí ẹni ń tú baba ẹni síhòòhò ni. O kò gbọdọ̀ bá arabinrin rẹ lòpọ̀, kì báà jẹ́ ọmọ ìyá rẹ lobinrin, tabi ọmọ baba rẹ lobinrin, kì báà jẹ́ pé ilé ni wọ́n bí i sí tabi ìdálẹ̀. O kò gbọdọ̀ bá ọmọ ọmọ rẹ lobinrin lòpọ̀, kì báà jẹ́ ọmọ ọmọ rẹ obinrin tabi ọmọ ọmọ rẹ ọkunrin, nítorí ohun ìtìjú ni ó jẹ́ fún ọ, nítorí pé, ìhòòhò wọn jẹ́ ìhòòhò rẹ. O kò gbọdọ̀ bá ọmọ tí aya baba rẹ bá bí fún baba rẹ lòpọ̀, nítorí pé, arabinrin rẹ ni. O kò gbọdọ̀ bá arabinrin baba rẹ lòpọ̀, nítorí pé, ẹbí baba rẹ ni ó jẹ́. O kò gbọdọ̀ bá arabinrin ìyá rẹ lòpọ̀, nítorí pé, ẹbí ìyá rẹ ni ó jẹ́. O kò gbọdọ̀ bá aya arakunrin baba rẹ lòpọ̀, nítorí pé, ẹ̀gbọ́n ni ó jẹ́ fún ọ. O kò gbọdọ̀ bá aya ọmọ rẹ lòpọ̀, nítorí pé, aya ọmọ rẹ ni. O kò gbọdọ̀ bá aya arakunrin rẹ lòpọ̀, nítorí pé, ohun ìtìjú ni, ìhòòhò arakunrin rẹ ni. O kò gbọdọ̀ bá obinrin kan lòpọ̀ tán, kí o tún bá ọmọ rẹ̀ obinrin lòpọ̀ tabi ọmọ ọmọ rẹ̀, kì báà jẹ́ ọmọ ọmọ rẹ̀ ọkunrin tabi ọmọ ọmọ rẹ̀ obinrin, nítorí pé, ẹbí rẹ̀ ni wọ́n jẹ́, ìwà burúkú ni èyí jẹ́. O kò gbọdọ̀ fi ọmọ ìyá, tabi ọmọ baba iyawo rẹ ṣe aya níwọ̀n ìgbà tí aya rẹ tí í ṣe ẹ̀gbọ́n rẹ̀ bá wà láàyè. “O kò gbọdọ̀ bá obinrin lòpọ̀, nígbà tí ó bá ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀ lọ́wọ́. O kò gbọdọ̀ bá aya aládùúgbò rẹ lòpọ̀, kí o sì sọ ara rẹ di aláìmọ́ pẹlu rẹ̀. O kò gbọdọ̀ fa èyíkéyìí ninu àwọn ọmọ rẹ kalẹ̀ fún lílò níbi ìbọ̀rìṣà Moleki, kí o sì ti ipa bẹ́ẹ̀ ba orúkọ Ọlọrun rẹ jẹ́. Èmi ni OLUWA. O kò gbọdọ̀ bá ọkunrin lòpọ̀ gẹ́gẹ́ bí obinrin, ohun ìríra ni. O kò sì gbọdọ̀ bá ẹranko lòpọ̀, bẹ́ẹ̀ ni obinrin kò sì gbọdọ̀ fi ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ẹranko láti bá a lòpọ̀; ìwà burúkú ni. “Má ṣe fi èyíkéyìí ninu àwọn nǹkan tí a dárúkọ wọnyi ba ara rẹ jẹ́, nítorí pé, nǹkan wọnyi ni àwọn orílẹ̀-èdè tí mò ń lé jáde kúrò níwájú yín fi ba ara wọn jẹ́. Ilẹ̀ náà di ìbàjẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí mo fi ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn jẹ ẹ́, ilẹ̀ náà sì ń ti àwọn eniyan inú rẹ̀ jáde. Ẹ gbọdọ̀ pa àwọn ìlànà, ati àwọn òfin mi wọnyi mọ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe èyíkéyìí ninu àwọn ohun ìríra wọnyi, kì báà jẹ́ onílé ninu yín, tabi àlejò tí ń ṣe àtìpó láàrin yín. Nítorí pé gbogbo àwọn ohun ìríra wọnyi ni àwọn tí wọ́n ti gbé ilẹ̀ náà ṣáájú yín ti ṣe, tí wọ́n sì fi ba ilẹ̀ náà jẹ́. Kí ilẹ̀ náà má baà ti ẹ̀yin náà jáde nígbà tí ẹ bá bà á jẹ́, bí ó ti ti àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀ ṣáájú yín jáde. Nítorí pé, a óo yọ àwọn tí wọ́n bá ṣe àwọn ohun ìríra kúrò láàrin àwọn eniyan wọn. “Nítorí náà, ẹ pa àwọn àṣẹ mi mọ́, kí ẹ má sì ṣe èyíkéyìí ninu àwọn ohun ìríra wọnyi, tí àwọn tí wọ́n ṣáájú yín ṣe, kí ẹ má fi wọ́n ba ara yín jẹ́. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.” OLUWA sọ fún Mose pé kí ó sọ fún ìjọ eniyan Israẹli pé “Ẹ jẹ́ mímọ́, nítorí pé, mímọ́ ni èmi OLUWA Ọlọrun yín. Olukuluku yín gbọdọ̀ bọ̀wọ̀ fún ìyá ati baba rẹ̀, kí ó sì pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín. “Ẹ kò gbọdọ̀ yipada kí ẹ lọ bọ oriṣa tabi kí ẹ yá ère kankan fún ara yín. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín. “Nígbà tí ẹ bá rú ẹbọ alaafia sí OLUWA, ẹ rú u ní ọ̀nà tí yóo fi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà. Ní ọjọ́ tí ẹ bá rú ẹbọ náà gan-an tabi ní ọjọ́ keji rẹ̀ ni ẹ gbọdọ̀ jẹ ohun tí ẹ fi rúbọ tán. Bí ohunkohun bá kù di ọjọ́ kẹta, sísun ni ẹ gbọdọ̀ dáná sun ún. Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ẹ́ ní ọjọ́ kẹta, ohun ìríra ni, kò sì ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà mọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì jẹ ẹ́ yóo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, nítorí pé, ó ti ba ohun mímọ́ OLUWA jẹ́, a óo yọ ọ́ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀. “Nígbà tí o bá ń kórè oko rẹ, o kò gbọdọ̀ kórè títí kan ààlà. Lẹ́yìn tí o bá ti kórè tán, o kò gbọdọ̀ pada lọ tún kórè àwọn ohun tí o bá gbàgbé. O kò gbọdọ̀ kórè gbogbo àjàrà rẹ tán patapata, o kò sì gbọdọ̀ ṣa àwọn èso tí ó bá rẹ̀ sílẹ̀ ninu ọgbà àjàrà rẹ, o níláti fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn talaka ati àwọn àlejò. Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ. “Ẹ kò gbọdọ̀ jalè, ẹ kò gbọdọ̀ fi ìwà ẹ̀tàn bá ara yín lò; ẹ kò sì gbọdọ̀ parọ́ fún ara yín. Ẹ kò gbọdọ̀ fi orúkọ mi búra èké, kí ẹ má baà ba orúkọ Ọlọrun yín jẹ́. Èmi ni OLUWA. “Ẹ kò gbọdọ̀ pọ́n aládùúgbò yín lójú tabi kí ẹ jà á lólè; owó iṣẹ́ tí alágbàṣe bá ba yín ṣe kò gbọdọ̀ di ọjọ́ keji lọ́wọ́ yín. Ẹ kò gbọdọ̀ gbé adití ṣépè tabi kí ẹ gbé ohun ìdìgbòlù kalẹ̀ níwájú afọ́jú, ṣugbọn ẹ níláti bẹ̀rù Ọlọrun yín. Èmi ni OLUWA. “Ẹ kò gbọdọ̀ dájọ́ èké, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe ojuṣaaju sí talaka tabi ọlọ́rọ̀, ṣugbọn ẹ gbọdọ̀ máa dá ẹjọ́ àwọn aládùúgbò yín pẹlu òdodo. Ẹ kò gbọdọ̀ máa ṣe òfófó káàkiri láàrin àwọn eniyan yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ kọ̀ láti jẹ́rìí aládùúgbò yín, bí ẹ̀rí yín bá lè gba ẹ̀mí rẹ̀ là. Èmi ni OLUWA. “Ẹ kò gbọdọ̀ di arakunrin yín sinu, ṣugbọn ẹ gbọdọ̀ máa sọ àsọyé pẹlu aládùúgbò yín, kí ẹ má baà gbẹ̀ṣẹ̀ nítorí tirẹ̀. Ẹ kò gbọdọ̀ gbẹ̀san, tabi kí ẹ di ọmọ eniyan yín sinu, ṣugbọn ẹ níláti fẹ́ràn ọmọnikeji yín gẹ́gẹ́ bí ara yín. Èmi ni OLUWA. “Ẹ gbọdọ̀ pa àwọn ìlànà mi mọ́, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí oríṣìí meji ninu àwọn ohun ọ̀sìn yín gun ara wọn, ẹ kò gbọdọ̀ gbin oríṣìí èso meji sinu oko kan náà, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ fi oríṣìí aṣọ meji dá ẹ̀wù kan ṣoṣo. “Bí ọkunrin kan bá bá ẹrubinrin tí ó jẹ́ àfẹ́sọ́nà ẹlòmíràn lòpọ̀, tí wọn kò bá tíì ra ẹrubinrin náà pada, tabi kí wọ́n fún un ní òmìnira rẹ̀, kí wọ́n wádìí ọ̀rọ̀ náà, ṣugbọn wọn kò gbọdọ̀ tìtorí pé ẹrú ni kí wọn pa wọ́n. Ṣugbọn ọkunrin náà gbọdọ̀ mú àgbò kan tọ OLUWA wá ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, kí ó fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi fún ara rẹ̀. Alufaa yóo fi àgbò ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi náà ṣe ètùtù fún un níwájú OLUWA nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, OLUWA yóo sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì í. “Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà, tí ẹ bá sì gbin oríṣìíríṣìí igi eléso fún jíjẹ, ẹ ka gbogbo èso tí wọ́n bá so fún ọdún mẹta ti àkọ́kọ́ sí aláìmọ́; èèwọ̀ ni, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́. Ní ọdún kẹrin, ẹ ya gbogbo àwọn èso náà sọ́tọ̀ fún rírú ẹbọ ọpẹ́ sí OLUWA. Ṣugbọn ní ọdún karun-un, ẹ lè jẹ èso wọn, kí wọ́n lè máa so sí i lọpọlọpọ. Èmi ni OLUWA. “Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran pẹlu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ lọ máa woṣẹ́, tabi kí ẹ gba àjẹ́. Diut 18:10 Ẹ kò gbọdọ̀ gé ẹsẹ̀ irun orí yín tabi kí ẹ gé ẹsẹ̀ irùngbọ̀n yín. Ẹ kò gbọdọ̀ ya ara yín lábẹ nítorí òkú, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ fín ara yín rárá. Èmi ni OLUWA. “Ẹ kò gbọdọ̀ ba ọmọbinrin yín jẹ́, nípa fífi ṣe aṣẹ́wó; kí ilẹ̀ náà má baà di ilẹ̀ àgbèrè, kí ó sì kún fún ìwà burúkú. Ẹ gbọdọ̀ pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, kí ẹ sì fi ọ̀wọ̀ wọ ilé mímọ́ mi. Èmi ni OLUWA. “Ẹ kò gbọdọ̀ kó ọ̀rọ̀ yín lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn aláyẹ̀wò tabi àwọn abókùúsọ̀rọ̀, kí wọ́n má baà sọ yín di aláìmọ́. Èmi ni OLUWA. “Ẹ máa bu ọlá fún àwọn ogbó, kí ẹ máa bọ̀wọ̀ fún àwọn àgbà; kí ẹ sì máa bẹ̀rù Ọlọrun yín. Èmi ni OLUWA. “Nígbà tí àlejò kan bá wọ̀ tì yín ninu ilẹ̀ yín, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe é ní ibi. Bí ẹ ti ń ṣe sí ọmọ onílé ni kí ẹ máa ṣe sí àlejò tí ó wọ̀ sọ́dọ̀ yín, ẹ fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara yín, nítorí pé ẹ̀yin pàápàá ti jẹ́ àlejò rí ní ilẹ̀ Ijipti. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín. “Ẹ kò gbọdọ̀ ṣèrú nígbà tí ẹ bá ń wọn nǹkan fún eniyan, kì báà jẹ́ ohun tí a fi ọ̀pá wọ̀n, tabi ohun tí a fi òṣùnwọ̀n wọ̀n, tabi ohun tí a kà, òṣùnwọ̀n yín gbọdọ̀ péye: ìwọ̀n efa tí ó péye ati ìwọ̀n hini tí ó péye ni ẹ gbọdọ̀ máa lò. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó kó yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti wá. Ẹ gbọdọ̀ máa pa gbogbo ìlànà mi mọ́, kí ẹ sì máa tẹ̀lé gbogbo òfin mi. Èmi ni OLUWA.” OLUWA sọ fún Mose pé kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹnikẹ́ni ninu wọn ati àwọn àlejò, tí wọn ń ṣe àtìpó ní ààrin wọn tí ó bá fi èyíkéyìí ninu àwọn ọmọ rẹ̀ fún oriṣa Moleki, pípa ni kí wọ́n pa á; kí àwọn eniyan ilẹ̀ náà sọ ọ́ ní òkúta pa. Èmi gan-an yóo kẹ̀yìn sí olúwarẹ̀, n óo sì yọ ọ́ kúrò lára àwọn eniyan rẹ̀; nítorí pé ó ti fi ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ fún oriṣa Moleki, ó sì ti sọ ibi mímọ́ mi di aláìmọ́, ati pé ó ti ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́. Bí àwọn eniyan tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà bá mójú fo ẹni tí ó bá fi ọmọ rẹ̀ fún oriṣa Moleki, tí wọn kò pa á, nígbà náà ni èmi gan-an yóo wá kẹ̀yìn sí olúwarẹ̀ ati gbogbo ìdílé rẹ̀, n óo sì yọ wọ́n kúrò lára àwọn eniyan wọn, ati òun, ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn rẹ̀, tí wọ́n jọ ń bọ oriṣa Moleki. “Bí ẹnìkan bá ń lọ ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀, tabi àwọn oṣó, tí ó sì ń tọ̀ wọ́n lẹ́yìn, n óo kẹ̀yìn sí olúwarẹ̀, n óo sì yọ ọ́ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀. Nítorí náà, ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì jẹ́ mímọ́, nítorí pé, èmi ni OLUWA Ọlọrun yín. Ẹ máa ṣàkíyèsí àwọn ìlànà mi, kí ẹ sì máa tẹ̀lé wọn. Èmi ni OLUWA tí ó sọ yín di mímọ́. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé baba tabi ìyá rẹ̀, pípa ni kí wọ́n pa á. Ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà lórí ara rẹ̀ nítorí pé ó ṣépè lé baba tabi ìyá rẹ̀. “Bí ẹnikẹ́ni bá bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀, pípa ni kí wọ́n pa olúwarẹ̀ ati obinrin tí ó bá lòpọ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá aya baba rẹ̀ lòpọ̀, ó dójúti baba rẹ̀, pípa ni kí wọ́n pa àwọn mejeeji, ẹ̀jẹ̀ wọn yóo wà lórí ara wọn. Bí ẹnikẹ́ni bá bá aya ọmọ rẹ̀ lòpọ̀, pípa ni kí wọ́n pa àwọn mejeeji; wọ́n ti hùwà ìbàjẹ́ láàrin ẹbí, ẹ̀jẹ̀ wọn yóo wà lórí ara wọn. Bí ọkunrin kan bá bá ọkunrin ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lòpọ̀ bí a ti ń bá obinrin lòpọ̀, àwọn mejeeji ti ṣe ohun ìríra; pípa ni kí wọ́n pa wọ́n, ẹ̀jẹ̀ wọn yóo wà lórí ara wọn. Bí ẹnìkan bá fẹ́ iyawo, tí ó sì tún fẹ́ ìyá iyawo náà pẹlu, ìwà burúkú ni; sísun ni kí wọ́n sun wọ́n níná, ati ọkunrin ati àwọn obinrin mejeeji, kí ìwà burúkú má baà wà láàrin yín. Bí ọkunrin kan bá bá ẹranko lòpọ̀, pípa ni kí ẹ pa òun ati ẹranko náà. Bí obinrin bá tọ ẹranko lọ, tí ó sì tẹ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ fún un láti bá a lòpọ̀, pípa ni kí ẹ pa òun ati ẹranko náà, ẹ̀jẹ̀ wọn yóo wà lórí ara wọn. “Bí ọkunrin kan bá bá arabinrin rẹ̀ lòpọ̀, kì báà jẹ́ ọmọ baba rẹ̀ tabi ọmọ ìyá rẹ̀, tí wọ́n sì rí ìhòòhò ara wọn, ohun ìtìjú ni; lílé ni kí wọ́n lé wọn jáde kúrò ní àdúgbò, kí wọ́n sì yọ wọ́n kúrò láàrin àwọn eniyan wọn, nítorí pé ó ti bá arabinrin rẹ̀ lòpọ̀. Orí rẹ̀ ni yóo sì fi ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Bí ọkunrin kan bá bá obinrin lòpọ̀ ní àkókò tí obinrin yìí ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀, lílé ni kí wọ́n lé àwọn mejeeji kúrò ní àdúgbò, kí wọ́n sì yọ wọ́n kúrò láàrin àwọn eniyan wọn. “Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ bá arabinrin ìyá rẹ, tabi arabinrin baba rẹ lòpọ̀, nítorí pé, ìwà ìbàjẹ́ ni láàrin ẹbí. Àwọn mejeeji yóo sì fi orí ara wọn ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Bí ẹnìkan bá bá aya arakunrin baba rẹ̀ lòpọ̀, ohun ìtìjú ni ó ṣe sí arakunrin baba rẹ̀. Àwọn mejeeji yóo sì fi orí ara wọn ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọn yóo kú láì bímọ. Bí ọkunrin kan bá bá aya ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lòpọ̀, tabi aya àbúrò rẹ̀, ohun àìmọ́ ni, ohun ìtìjú ni ó sì ṣe sí ẹ̀gbọ́n tabi àbúrò rẹ̀, àwọn mejeeji yóo kú láì bímọ. “Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ kíyèsí gbogbo àwọn ìlànà mi ati àwọn òfin mi, kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́, kí ilẹ̀ tí mò ń ko yín lọ má baà tì yín jáde. Ẹ kò sì gbọdọ̀ kọ́ àṣà àwọn orílẹ̀-èdè tí n óo lé jáde fun yín, nítorí pé tìtorí gbogbo ohun tí wọn ń ṣe wọnyi ni mo fi kórìíra wọn. Ṣugbọn mo ti ṣèlérí fun yín pé, ẹ̀yin ni ẹ ó jogún ilẹ̀ wọn, n óo fi ilẹ̀ tí ó lẹ́tù lójú, tí ó sì ń ṣàn fún wàrà ati oyin fun yín, gẹ́gẹ́ bí ohun ìní. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó yà yín sọ́tọ̀ kúrò lára gbogbo eniyan. Nítorí náà, ẹ níláti mọ ìyàtọ̀ láàrin àwọn ẹran tí ó mọ́ ati àwọn tí kò mọ́; ati láàrin àwọn ẹyẹ tí ó mọ́ ati àwọn tí kò mọ́. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹyẹ tabi ẹranko kankan tabi àwọn ẹ̀dá alààyè tí ń káàkiri lórí ilẹ̀, tí mo ti yà sọ́tọ̀ fun yín pé wọ́n jẹ́ aláìmọ́. Ẹ níláti jẹ́ mímọ́ fún mi, nítorí pé, mímọ́ ni èmi OLUWA, mo sì ti yà yín sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn eniyan kí ẹ lè máa jẹ́ tèmi. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ abókùúsọ̀rọ̀ tabi oṣó, pípa ni kí ẹ pa á; ẹ sọ wọ́n ní òkúta pa ni, ẹ̀jẹ̀ wọn yóo sì wà lórí ara wọn.” OLUWA sọ fún Mose pé kí ó sọ fún àwọn alufaa, àwọn ọmọ Aaroni pé, “Ẹnikẹ́ni ninu wọn kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nítorí ikú àwọn eniyan rẹ̀. Àfi ti àwọn tí wọ́n bá súnmọ́ wọn, bíi ìyá tabi baba rẹ̀; tabi ọmọ tabi arakunrin rẹ̀, tabi ti arabinrin rẹ̀ tí kò tíì mọ ọkunrin, (tí ń gbé ọ̀dọ̀ rẹ̀, nítorí pé kò tíì ní ọkọ, nítorí tirẹ̀, alufaa náà lè sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́). Kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, kí ó sì ba ara rẹ̀ jẹ́, nítorí olórí ló jẹ́ láàrin àwọn eniyan rẹ̀. “Alufaa kò gbọdọ̀ ṣọ̀fọ̀ débi pé kí ó fá irun rẹ̀, tabi kí ó gé ẹsẹ̀ irùngbọ̀n rẹ̀ tabi kí ó fi abẹ ya ara rẹ̀. Wọ́n níláti jẹ́ mímọ́ fún Ọlọrun wọn, wọn kò sì gbọdọ̀ sọ orúkọ Ọlọrun wọn di aláìmọ́, nítorí pé àwọn ni wọ́n ń rú ẹbọ sísun sí OLUWA; èyí tíí ṣe oúnjẹ Ọlọrun wọn, nítorí náà wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́. Nítorí pé alufaa jẹ́ ẹni mímọ́ fún Ọlọrun rẹ̀, kò gbọdọ̀ gbé aṣẹ́wó ní iyawo, tabi obinrin tí ó ti di aláìmọ́, tabi obinrin tí ó ti kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀. Ẹ gbọdọ̀ ka alufaa sí ẹni mímọ́, nítorí òun ni ó ń rú ẹbọ ohun jíjẹ sí Ọlọrun yín. Ó níláti jẹ́ ẹni mímọ́ fun yín, nítorí pé èmi OLUWA tí mo yà yín sí mímọ́ jẹ́ mímọ́. Ọmọ alufaa lobinrin, tí ó bá sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nípa ṣíṣe àgbèrè káàkiri, sọ baba rẹ̀ di aláìmọ́, nítorí náà sísun ni kí ẹ dáná sun ọmọ náà. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ alufaa àgbà láàrin àwọn arakunrin rẹ̀, tí wọ́n ti ta òróró sí lórí láti yà á sọ́tọ̀, kí ó lè máa wọ àwọn aṣọ mímọ́, kò gbọdọ̀ jẹ́ kí irun orí rẹ̀ rí játijàti; kò sì gbọdọ̀ fa aṣọ rẹ̀ ya, láti fi hàn pé ó ń ṣọ̀fọ̀. Kò gbọdọ̀ lọ sí ibi tí wọ́n bá tẹ́ òkú sí, tabi kí ó sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, kì báà jẹ́ òkú baba rẹ̀ tabi ti ìyá rẹ̀. Kò sì gbọdọ̀ jáde kúrò ninu ibi mímọ́ náà, tabi kí ó sọ ibi mímọ́ Ọlọrun rẹ̀ di aláìmọ́, nítorí pé, òróró ìyàsímímọ́ Ọlọrun rẹ̀ wà lórí rẹ̀. Èmi ni OLUWA. Obinrin tí kò bá tíì mọ ọkunrin rí ni ó gbọdọ̀ fẹ́ níyàwó. Kò gbọdọ̀ fi opó ṣe aya tabi obinrin tí ó kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀, tabi obinrin tí ó ti mọ ọkunrin, tabi aṣẹ́wó; kò gbọdọ̀ fẹ́ èyíkéyìí ninu wọn. Obinrin tí kò tíì mọ ọkunrin rí ni kí ó fẹ́ láàrin àwọn eniyan rẹ̀. Kí ó má baà sọ àwọn ọmọ rẹ̀ di aláìmọ́ láàrin àwọn eniyan rẹ̀; nítorí pé èmi ni OLUWA, tí mo sọ ọ́ di mímọ́.” OLUWA sọ fún Mose, kí ó sọ fún Aaroni pé, “Èyíkéyìí ninu arọmọdọmọ rẹ̀ tí ó bá ní àbùkù kankan kò gbọdọ̀ rú ẹbọ ohun jíjẹ sí Ọlọrun rẹ̀. Nítorí pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ní àbùkù kò gbọdọ̀ súnmọ́ ibi pẹpẹ láti rú ẹbọ, kì báà jẹ́ afọ́jú, tabi arọ, ẹni tí ijamba bá bà lójú jẹ́, tabi tí apá tabi ẹsẹ̀ rẹ̀ kan gùn ju ekeji lọ, tabi tí ijamba bá ṣe ní ọwọ́ kan tabi ẹsẹ̀ kan, tabi abuké, aràrá, tabi ẹni tí kò ríran dáradára, tabi ẹni tí ó ní àrùn ẹ̀yi tabi ìpẹ́pẹ́, tabi ẹni tí ó jẹ́ ìwẹ̀fà. Èyíkéyìí ninu arọmọdọmọ Aaroni, alufaa tí ó bá ti ní àbùkù kan lára kò gbọdọ̀ súnmọ́ ibi pẹpẹ láti rú ẹbọ sísun sí èmi OLUWA, níwọ̀n ìgbà tí ó bá ṣì ní àbùkù lára, kò gbọdọ̀ súnmọ́ ibi pẹpẹ láti rú ẹbọ ohun jíjẹ sí Ọlọrun rẹ̀. Ó lè jẹ ohun jíjẹ ti Ọlọrun rẹ̀, kì báà ṣe ninu èyí tí ó mọ́ jùlọ tabi ninu àwọn ohun tí ó mọ́. Ṣugbọn kò gbọdọ̀ súnmọ́ tòsí ibi aṣọ ìbòjú náà tabi kí ó wá sí ibi pẹpẹ, nítorí pé ó ní àbùkù, kí ó má baà sọ àwọn ibi mímọ́ mi di aláìmọ́; èmi ni OLUWA tí mo sọ wọ́n di mímọ́.” Mose sì sọ gbogbo nǹkan tí OLUWA rán an fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati fún gbogbo àwọn eniyan Israẹli. OLUWA rán Mose pé, “Sọ fún Aaroni ati àwọn ọmọkunrin rẹ̀ pé, kí wọ́n máa fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ lo àwọn nǹkan mímọ́ tí àwọn eniyan Israẹli yà sọ́tọ̀ fún mi, kí wọ́n má baà ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́. Èmi ni OLUWA. Bí èyíkéyìí ninu arọmọdọmọ wọn bá súnmọ́ àwọn nǹkan mímọ́ wọ̀n-ọn-nì, tí àwọn eniyan Israẹli ti yà sí mímọ́ fún OLUWA; nígbà tí ó wà ní ipò àìmọ́, a óo mú ẹni náà kúrò lọ́dọ̀ mi. Èmi ni OLUWA. “Ẹnikẹ́ni ninu ìran Aaroni tí ó bá ní àrùn ẹ̀tẹ̀, tabi tí ara rẹ̀ bá ń tú, kò gbọdọ̀ jẹ ninu àwọn ohun mímọ́ náà, títí tí yóo fi di mímọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan ohunkohun tí ó jẹ́ aláìmọ́, kì báà jẹ́ pé ó fara kan òkú ni, tabi pé ó fara kan ẹni tí nǹkan ọkunrin jáde lára rẹ̀, tabi ẹni tí ó bá fara kan èyíkéyìí ninu àwọn ẹ̀dá alààyè tí ń káàkiri, èyí tí ó lè sọ eniyan di aláìmọ́, tabi ẹnikẹ́ni tí ó lè kó àìmọ́ bá eniyan, ohun yòówù tí àìmọ́ rẹ̀ lè jẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan irú nǹkan bẹ́ẹ̀, tabi irú ẹni bẹ́ẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́; kò sì ní jẹ ninu àwọn ohun mímọ́ náà títí tí yóo fi wẹ̀. Nígbà tí oòrùn bá wọ̀, yóo di mímọ́, lẹ́yìn náà, ó lè jẹ ninu àwọn ohun mímọ́ náà nítorí oúnjẹ rẹ̀ ni wọ́n jẹ́. Alufaa kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó bá kú fúnrara rẹ̀, tabi tí ẹranko burúkú bá pa; kí ó má baà fi òkú ẹran yìí sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́. Èmi ni OLUWA. “Àwọn alufaa gbọdọ̀ pa àwọn òfin mi mọ́, kí wọ́n má baà dẹ́ṣẹ̀ nítorí rẹ̀, kí wọ́n sì kú nítorí àwọn òfin mi tí wọ́n bá rú. Èmi ni OLUWA tí mo sọ wọ́n di mímọ́. “Àjèjì kankan kò gbọdọ̀ jẹ ninu àwọn ohun mímọ́, bẹ́ẹ̀ ni àlejò tabi alágbàṣe tí ń gbé ilé alufaa kò gbọdọ̀ jẹ ninu wọn. Ṣugbọn bí alufaa bá fi owó ra ẹrú fún ara rẹ̀, ẹrú náà lè jẹ ninu àwọn ohun mímọ́ náà. Àwọn ọmọ tí ẹrú náà bá sì bí ninu ilé alufaa náà lè jẹ ninu oúnjẹ náà pẹlu. Bí ọmọbinrin alufaa kan bá fẹ́ àjèjì, kò gbọdọ̀ jẹ ninu àwọn ohun mímọ́ tí wọ́n bá fi rúbọ. Ṣugbọn bí ọmọbinrin alufaa kan bá jẹ́ opó, tabi tí ó ti kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ láì bímọ fún un, tí ó bá pada sí ilé baba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ó wà ní ọdọmọbinrin, ó lè jẹ ninu oúnjẹ baba rẹ̀; sibẹsibẹ àjèjì kankan kò gbọdọ̀ jẹ ninu rẹ̀. “Bí ẹnìkan bá jẹ ohun mímọ́ kan ní ìjẹkújẹ yóo san án pada fún alufaa pẹlu ìdámárùn-ún rẹ̀. Àwọn alufaa kò gbọdọ̀ sọ àwọn ohun mímọ́ àwọn eniyan Israẹli tí wọ́n fi ń rúbọ sí OLUWA di aláìmọ́. Kí wọ́n má baà mú àwọn eniyan náà dẹ́ṣẹ̀, kí wọ́n sì kó ẹ̀bi rù wọ́n nípa jíjẹ àwọn ohun mímọ́ wọn; nítorí èmi ni OLUWA tí mo sọ wọ́n di mímọ́.” OLUWA tún rán Mose pé kí ó sọ fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati gbogbo àwọn eniyan Israẹli pé: “Nígbà tí ẹnìkan ninu àwọn eniyan Israẹli tabi àlejò tí ó wà láàrin wọn bá mú ohun ìrúbọ rẹ̀ wá, kì báà ṣe pé láti fi san ẹ̀jẹ́ kan ni, tabi gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àtinúwá, láti fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA, kí ohun ìrúbọ náà baà lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà, ó níláti jẹ́ akọ, tí kò ní àbùkù, ó lè jẹ́ akọ mààlúù, tabi àgbò, tabi òbúkọ. Ẹ kò gbọdọ̀ fi ohunkohun tí ó bá ní àbààwọ́n rúbọ, nítorí pé, OLUWA kò ní tẹ́wọ́gbà á lọ́wọ́ yín. Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ rú ẹbọ alaafia sí OLUWA láti san ẹ̀jẹ́, tabi fún ọrẹ àtinúwá; kì báà jẹ́ láti inú agbo mààlúù tabi láti inú agbo aguntan ni yóo ti mú ẹran ìrúbọ yìí, ó níláti jẹ́ pípé, kò gbọdọ̀ ní àbùkù kan lára, kí ẹbọ náà lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà. Bí ẹran náà bá jẹ́ afọ́jú, tabi amúkùn-ún, tabi ẹran tí ó farapa, tabi tí ara rẹ̀ ń tú, tabi tí ó ní èkúkú, ẹ kò gbọdọ̀ fi wọ́n fún OLUWA, tabi kí ẹ fi wọ́n rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ sí OLUWA. Bí apá tabi ẹsẹ̀ mààlúù tabi àgbò kan bá gùn ju ekeji lọ, ẹ lè mú un wá fún OLUWA gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ àtinúwá, ṣugbọn OLUWA kò ní tẹ́wọ́gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹran ìrúbọ láti fi san ẹ̀jẹ́. Bí wọ́n bá tẹ ẹran kan lọ́dàá, tabi bí kóró abẹ́ rẹ̀ bá fọ́, tabi tí abẹ́ rẹ̀ fàya, tabi tí wọ́n la abẹ́ rẹ̀, tabi tí wọ́n ṣá a lọ́gbẹ́ ní abẹ́, ẹ kò gbọdọ̀ mú un wá fún OLUWA, tabi kí ẹ fi rúbọ ninu gbogbo ilẹ̀ yín. “Bí ẹ bá gba irú ẹran bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ àlejò, ẹ kò gbọdọ̀ fi rú ẹbọ ohun jíjẹ sí èmi Ọlọrun yín. Níwọ̀n ìgbà tí àbùkù bá ti wà lára wọn, OLUWA kò ní tẹ́wọ́gba irú wọn lọ́wọ́ yín, nítorí àbùkù náà.” OLUWA sọ fún Mose pé: “Nígbà tí mààlúù, aguntan, tabi ewúrẹ́ bá bímọ, ẹ fi ọmọ náà sílẹ̀ pẹlu rẹ̀ fún ọjọ́ meje, láti ọjọ́ kẹjọ lọ ni ó tó lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún ẹbọ sísun sí OLUWA. Ẹ kò gbọdọ̀ fi ìyá ẹran ati ọmọ rẹ̀ rúbọ ní ọjọ́ kan náà; kì báà jẹ́ mààlúù, tabi aguntan, tabi ewúrẹ́. Nígbà tí ẹ bá sì ń rú ẹbọ ọpẹ́ sí OLUWA, ẹ gbọdọ̀ rú u ní ọ̀nà tí yóo fi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà. Ẹ níláti jẹ gbogbo rẹ̀ tán ní ọjọ́ kan náà, kò gbọdọ̀ kù di òwúrọ̀ ọjọ́ keji. Èmi ni OLUWA. “Ẹ gbọdọ̀ ṣàkíyèsí òfin mi, kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́. Èmi ni OLUWA. Ẹ kò gbọdọ̀ ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́, ẹ gbọdọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún mi láàrin gbogbo eniyan Israẹli. Èmi ni OLUWA tí mo sọ yín di mímọ́, tí mo sì ko yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, láti máa jẹ́ Ọlọrun yín. Èmi ni OLUWA.” OLUWA sọ fún Mose pé kí ó sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, “Àwọn àjọ̀dún tí èmi OLUWA yàn tí ó gbọdọ̀ kéde gẹ́gẹ́ bí ìpéjọ mímọ́ nìwọ̀nyí: Ọjọ́ mẹfa ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣugbọn ọjọ́ keje jẹ́ ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀, ati ọjọ́ ìpéjọ mímọ́. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà, ọjọ́ ìsinmi ni fún OLUWA ní gbogbo ibùgbé yín. Èyí ni àwọn àjọ̀dún ati àpèjọ tí OLUWA yàn, tí wọ́n gbọdọ̀ kéde, ní àkókò tí OLUWA yàn fún wọn. “Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrinla oṣù kinni ni kí ẹ máa ṣe àjọ ìrékọjá OLUWA. Ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù kan náà sì ni àjọ àìwúkàrà OLUWA. Ọjọ́ meje gbáko ni ẹ gbọdọ̀ fi máa jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà. Ní ọjọ́ kinni, ẹ níláti ní àpèjọ, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ tí ó bá lágbára. Ṣugbọn, ẹ óo máa rú ẹbọ sísun sí OLUWA fún ọjọ́ meje náà, ọjọ́ àpèjọ mímọ́ ni ọjọ́ keje yóo jẹ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ tí ó lágbára.” OLUWA tún rán Mose pé kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí n óo fun yín, tí ẹ bá sì ń kórè nǹkan inú rẹ̀, ẹ níláti gbé ìtí ọkà kan lára àkọ́so oko yín tọ alufaa lọ. Nígbà tí ó bá di ọjọ́ keji, lẹ́yìn ọjọ́ ìsinmi, alufaa yóo fi ìtí ọkà náà rú ẹbọ fífì níwájú OLUWA, kí ẹ lè jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀. Ní ọjọ́ tí ẹ bá ń fi ìtí ọkà yín rú ẹbọ fífì, kí ẹ fi ọ̀dọ́ akọ aguntan ọlọ́dún kan, tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ sísun sí OLUWA. Ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ óo rú pẹlu rẹ̀ nìyí: ìdámárùn-ún ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun tí wọ́n fi òróró pò, ẹ óo fi rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA, kí ẹ sì fi idamẹrin ìwọ̀n hini ọtí waini rú ẹbọ ohun mímu pẹlu rẹ̀. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ burẹdi tabi ọkà, kì báà jẹ́ ọkà yíyan tabi tútù títí di ọjọ́ yìí, tí ẹ óo fi mú ẹbọ Ọlọrun yín wá, ìlànà ni èyí yóo jẹ́ fún ìrandíran yín, ní gbogbo ilẹ̀ yín. “Ẹ óo ka ọ̀sẹ̀ meje, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ keji ọjọ́ ìsinmi tí ẹ mú ìtí ọkà fún ẹbọ fífì wá fún OLUWA. Ẹ óo ka aadọta ọjọ́ títí dé ọjọ́ keji ọjọ́ ìsinmi keje, lẹ́yìn náà, ẹ óo mú ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ fi ọkà titun ṣe wá fún OLUWA. Ẹ óo mú burẹdi meji tí wọ́n fi ìdámárùn-ún ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára ṣe wá fún ẹbọ fífì; àwọn àkàrà náà yóo ní ìwúkàrà ninu, ẹ óo mú wọn tọ OLUWA wá gẹ́gẹ́ bí àkọ́so oko yín. Ẹ óo mú ọ̀dọ́ aguntan meje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbùkù lọ́wọ́, pẹlu ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan ati àgbò meji, nígbà tí ẹ bá ń kó àwọn ìṣù àkàrà meji náà bọ̀. Àwọn ni ẹ óo fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA; pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ, ati ẹbọ ohun mímu, ẹbọ tí a fi iná sun, olóòórùn dídùn, tí OLUWA gbádùn ni. Ẹ óo fi òbúkọ kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ẹ óo sì fi àgbò meji ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ alaafia. Alufaa yóo fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA, pẹlu burẹdi tí ẹ fi àkọ́so ọkà ṣe, ati àgbò meji náà, wọn yóo jẹ́ ọrẹ mímọ́ fún OLUWA, tí a óo yà sọ́tọ̀ fún àwọn alufaa. Ẹ pe àpèjẹ mímọ́ ní ọjọ́ náà; ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan ní ọjọ́ náà. Ìlànà ni èyí yóo jẹ́ fún arọmọdọmọ yín ní gbogbo ilẹ̀ yín títí lae. “Nígbà tí ẹ bá ń kórè oko yín, ẹ kò gbọdọ̀ kórè títí dé ààlà patapata. Lẹ́yìn tí ẹ bá ti kórè tán, ẹ kò gbọdọ̀ pada lọ tún kórè àwọn èso tí ẹ bá gbàgbé. Ẹ gbọdọ̀ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn talaka ati àwọn àlejò. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.” OLUWA sọ fun Mose pé kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹ ya ọjọ́ kinni oṣù keje sọ́tọ̀ fún ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀. Yóo jẹ́ ọjọ́ ìrántí, ẹ óo kéde rẹ̀ pẹlu ìró fèrè, ẹ óo sì ní àpèjọ mímọ́. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kan, ẹ sì níláti rú ẹbọ sísun sí OLUWA.” OLUWA sọ fún Mose pé, “Ọjọ́ kẹwaa oṣù keje ni ọjọ́ ètùtù. Ẹ ní ìpéjọpọ̀ mímọ́ ní ọjọ́ náà, kí ẹ gbààwẹ̀, kí ẹ sì rú ẹbọ sísun sí OLUWA. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà, nítorí ọjọ́ ètùtù ni, tí wọn yóo ṣe ètùtù fun yín níwájú OLUWA Ọlọrun yín. Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbààwẹ̀ ní ọjọ́ náà, a óo yọ ọ́ kúrò lára àwọn eniyan rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà, n óo pa á run láàrin àwọn eniyan rẹ̀. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ rárá, ìlànà ni ó jẹ́ títí lae fún ìrandíran yín, ní gbogbo ibùgbé yín. Yóo jẹ́ ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀, ẹ sì gbọdọ̀ gbààwẹ̀. Ọjọ́ ìsinmi náà yóo bẹ̀rẹ̀ láti ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹsan-an títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹwaa.” OLUWA sọ fún Mose pé kí ó sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, “Láti ọjọ́ kẹẹdogun oṣù keje lọ, ẹ óo ṣe àjọ̀dún Àgọ́ fún OLUWA; ọjọ́ meje ni ẹ óo fi ṣe é. Ìpéjọpọ̀ mímọ́ yóo wà ní ọjọ́ kinni, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan ní ọjọ́ náà. Ọjọ́ meje ni ẹ óo fi máa rú ẹbọ sísun sí OLUWA. Ní ọjọ́ kẹjọ, ẹ óo ní ìpéjọpọ̀ mímọ́, ẹ óo sì rú ẹbọ sísun sí OLUWA. Ìpéjọpọ̀ tí ó lọ́wọ̀ ni, nítorí náà, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan. “Àwọn àjọ̀dún wọnyi ni OLUWA ti yà sọ́tọ̀; ẹ óo máa kéde wọn gẹ́gẹ́ bí àkókò ìpéjọpọ̀ mímọ́, láti máa rú ẹbọ tí a fi iná sun sí OLUWA, ẹbọ sísun, ati ẹbọ ohun jíjẹ; ati ẹbọ ohun mímu, olukuluku ní ọjọ́ tí a ti yàn fún wọn. Àwọn ẹbọ wọnyi wà lọ́tọ̀ ní tiwọn, yàtọ̀ sí ti àwọn ọjọ́ ìsinmi fún OLUWA, ati àwọn ẹ̀bùn yín, ati àwọn ẹbọ ẹ̀jẹ́ yín, ati àwọn ọrẹ ẹbọ àtinúwá tí ẹ óo máa mú wá fún OLUWA. “Lẹ́yìn tí ẹ bá ti kórè àwọn èso ilẹ̀ yín tán, láti ọjọ́ kẹẹdogun oṣù keje lọ, kí ẹ máa ṣe àjọ àjọ̀dún OLUWA fún ọjọ́ meje; ọjọ́ kinni ati ọjọ́ kẹjọ yóo jẹ́ ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀. Ní ọjọ́ kinni, ẹ óo mú ninu àwọn èso igi tí ó bá dára, ati imọ̀ ọ̀pẹ, ati ẹ̀ka igi tí ó ní ewé dáradára, ati ẹ̀ka igi wilo etí odò, kí ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín fún ọjọ́ meje. Ọjọ́ meje láàrin ọdún kan ni ẹ óo máa fi ṣe àjọ̀dún fún OLUWA; Ìlànà títí lae ni èyí jẹ́ fún arọmọdọmọ yín. Ninu oṣù keje ọdún ni ẹ óo máa ṣe àjọ àjọ̀dún náà. Inú àgọ́ ni ẹ óo máa gbé fún gbogbo ọjọ́ meje náà; gbogbo ẹni tí ó bá jẹ́ ọmọ Israẹli ni ó gbọdọ̀ gbé inú àgọ́, kí àwọn arọmọdọmọ yín lè mọ̀ pé, inú àgọ́ ni mo mú kí àwọn ọmọ Israẹli máa gbé nígbà tí mo kó wọn jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.” Bẹ́ẹ̀ ni Mose ṣe ṣàlàyé àwọn Àjọ àjọ̀dún tí OLUWA yàn, fún àwọn ọmọ Israẹli. OLUWA sọ fún Mose pé, “Pàṣẹ fún àwọn eniyan Israẹli pé kí wọn mú ojúlówó òróró olifi wá fún àtùpà ilé mímọ́ mi, kí ó lè máa wà ní títàn nígbà gbogbo. Ní ìrọ̀lẹ́, Aaroni yóo máa tan àtùpà náà kalẹ̀ níwájú aṣọ ìbòjú tí ó wà níwájú àpótí ẹ̀rí, wọn yóo máa wà ní títàn níwájú OLUWA títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji. Èyí yóo wà bí ìlànà, títí lae, fún arọmọdọmọ yín. Aaroni yóo sì máa ṣe ìtọ́jú àwọn àtùpà tí wọ́n wà lórí ọ̀pá fìtílà wúrà, kí wọ́n lè máa wà ní títàn níwájú OLUWA nígbà gbogbo. “Ẹ mú ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, kí ẹ sì fi ṣe burẹdi mejila, ìdámárùn-ún ìwọ̀n ìyẹ̀fun efa kan ni kí ẹ fi ṣe burẹdi kọ̀ọ̀kan. Ẹ sì máa tò wọ́n kalẹ̀ sí ọ̀nà meji; mẹfa mẹfa ní ọ̀nà kọ̀ọ̀kan, lórí tabili tí wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe. Ẹ fi ojúlówó turari sí ọ̀nà kọ̀ọ̀kan, kí wọ́n lè fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí OLUWA gẹ́gẹ́ bí àmì fún ìrántí. Ní gbogbo ọjọ́ ìsinmi, Aaroni yóo máa tò wọ́n kalẹ̀ níwájú OLUWA nígbà gbogbo, ní orúkọ àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bíi majẹmu títí lae. Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni wọ́n ni àwọn burẹdi náà, ibi mímọ́ ni wọn yóo sì ti máa jẹ wọ́n, nítorí pé òun ni ó mọ́ jùlọ ninu ìpín wọn, ninu ọrẹ ẹbọ sísun sí OLUWA.” Ọkunrin kan wà tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Israẹli, ṣugbọn tí baba rẹ̀ jẹ́ ará Ijipti. Ní ọjọ́ kan, nígbà tí ó bá àwọn ọmọ Israẹli jáde, ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàrin òun ati ọkunrin kan, tí ó jẹ́ ọmọ Israẹli, ní ibùdó. Ọkunrin tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Israẹli yìí bá sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ OLUWA, bí ó ti ń búra ni ó ń ṣépè. Wọ́n bá mú un tọ Mose wá; orúkọ ìyá ọmọkunrin náà ni Ṣelomiti ọmọ Dibiri láti inú ẹ̀yà Dani. Wọ́n tì í mọ́lé títí tí wọn fi mọ ohun tí OLUWA fẹ́ kí wọ́n ṣe sí i. OLUWA sọ fún Mose pé, “Mú ọkunrin tí ó ṣépè náà jáde kúrò láàrin ibùdó, kí gbogbo àwọn tí wọ́n gbọ́ nígbà tí ó ṣépè gbé ọwọ́ lé e lórí, kí gbogbo ìjọ eniyan sì sọ ọ́ ní òkúta pa. Wí fún àwọn eniyan Israẹli pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé Ọlọrun rẹ̀ yóo ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ nítorí rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ OLUWA, pípa ni wọn yóo pa á. Gbogbo ìjọ eniyan yóo sọ ọ́ ní òkúta pa, kì báà jẹ́ àlejò, kì báà jẹ́ onílé; tí ó bá ṣá ti sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ OLUWA, pípa ni wọn yóo pa á. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa eniyan, pípa ni wọn yóo pa òun náà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹran ẹlẹ́ran, yóo san án pada. Ohun tí ẹ̀tọ́ wí ni pé, kí á fi ẹ̀mí dípò ẹ̀mí. “Bí ẹnìkan bá ṣá aládùúgbò rẹ̀ lọ́gbẹ́, irú ọgbẹ́ tí ó ṣá aládùúgbò rẹ̀ gan-an ni wọn yóo ṣá òun náà. Bí ẹnìkan bá ṣe aládùúgbò rẹ̀ léṣe, tí ó sì di ohun àbùkù sí i lára, ohun tí ó ṣe sí aládùúgbò rẹ̀ ni kí wọ́n ṣe sí òun náà. Bí ó bá dá egungun aládùúgbò rẹ̀, kí wọ́n dá egungun tirẹ̀ náà, bí ó bá fọ́ ọ lójú, kí wọ́n fọ́ ojú tirẹ̀ náà, bí ó bá yọ eyín rẹ̀, kí wọ́n yọ eyín tirẹ̀ náà; irú ohun tí ó bá fi ṣe ẹlòmíràn gan-an ni kí wọn fi ṣe òun náà. Ẹni tí ó bá pa ẹran, yóo san òmíràn pada, ẹni tí ó bá sì pa eniyan, wọn yóo pa òun náà. Òfin kan náà tí ó de àlejò, ni ó gbọdọ̀ de onílé, nítorí pé èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.” Mose sọ ọ̀rọ̀ wọnyi fún àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. Wọ́n mú ọkunrin tí ó ṣépè náà jáde kúrò láàrin ibùdó, wọ́n sì sọ ọ́ ní òkúta pa. OLUWA bá Mose sọ̀rọ̀ lórí òkè Sinai, ó ní, “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí n óo fun yín, àkókò ìyàsọ́tọ̀ kan gbọdọ̀ wà fún ilẹ̀ náà tí yóo jẹ́ àkókò ìsinmi fún OLUWA. Ọdún mẹfa ni kí ẹ máa fi gbin èso sinu oko yín, ọdún mẹfa náà sì ni kí ẹ máa fi tọ́jú ọgbà àjàrà yín, tí ẹ óo sì máa fi kórè èso rẹ̀. Ṣugbọn ọdún keje yóo jẹ́ ọdún ìsinmi tí ó ní ọ̀wọ̀ fún ilẹ̀ náà, ilẹ̀ náà yóo sinmi fún OLUWA, ẹ kò gbọdọ̀ gbin ohunkohun sinu oko yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ tọ́jú àjàrà yín. Ohunkohun tí ó bá dá hù fún ara rẹ̀ ninu oko yín, ẹ kò gbọdọ̀ kórè rẹ̀. Ẹ kò gbọdọ̀ kórè èso tí ó bá so ninu ọgbà àjàrà yín tí ẹ kò tọ́jú. Ọdún náà gbọdọ̀ jẹ́ ọdún ìsinmi fún ilẹ̀. Ìsinmi ilẹ̀ yìí ni yóo mú kí oúnjẹ wà fun yín: ati ẹ̀yin alára, tọkunrin tobinrin yín, ati àwọn ẹrú, ati àwọn alágbàṣe yín, ati àwọn àlejò tí wọ́n ń ba yín gbé, ati àwọn ẹran ọ̀sìn yín, ati àwọn ẹranko ìgbẹ́ tí wọ́n wà ní ilẹ̀ yín, gbogbo èso ilẹ̀ náà yóo sì wà fún jíjẹ. “Ẹ ka ìsinmi ọdún keje keje yìí lọ́nà meje, kí ọdún keje náà fi jẹ́ ọdún mọkandinlaadọta. Nígbà tí ó bá di ọjọ́ kẹwaa oṣù keje tíí ṣe ọjọ́ ètùtù, ẹ óo rán ọkunrin kan kí ó lọ fọn fèrè jákèjádò gbogbo ilẹ̀ yín. Ẹ ya ọdún tí ó gbẹ̀yìn aadọta ọdún náà sí mímọ́, kí ẹ sì kéde ìdáǹdè jákèjádò gbogbo ilẹ̀ yín fún gbogbo àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀, yóo jẹ́ ọdún jubili fun yín. Ní ọdún náà, olukuluku yín yóo pada sórí ilẹ̀ rẹ̀ ati sinu ìdílé rẹ̀. Ọdún jubili ni ọdún tí ó gbẹ̀yìn aadọta ọdún yìí yóo jẹ́ fun yín. Ninu ọdún náà, ẹ kò gbọdọ̀ gbin ohunkohun, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ kórè ohun tí ó bá dá hù fúnra rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ ká àjàrà tí ó bá so ninu ọgbà àjàrà tí ẹ kò tọ́jú. Nítorí pé, ọdún jubili ni yóo máa jẹ́ fun yín, yóo jẹ́ ọdún mímọ́ fun yín, ninu oko ni ẹ óo ti máa jẹ ohun tí ó bá so. “Ní ọdún jubili yìí, olukuluku yín yóo pada sórí ilẹ̀ rẹ̀. Nítorí náà, nígbà tí ẹ bá ta ilẹ̀ fún aládùúgbò yín, tabi tí ẹ bá ń ra ilẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe àìdára sí ara yín. Iye ọdún tí ó bá ti rékọjá lẹ́yìn ọdún jubili ni ẹ óo máa wò ra ilẹ̀ lọ́wọ́ aládùúgbò yín, iye ọdún tí ẹ bá fi lè gbin ohun ọ̀gbìn sórí ilẹ̀ kan kí ọdún jubili tó dé ni òun náà yóo máa wò láti tà á fun yín. Tí ó bá jẹ́ pé ọdún pupọ ni ó kù, owó ilẹ̀ náà yóo pọ̀, ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé ọdún díẹ̀ ni, owó rẹ̀ yóo wálẹ̀; nítorí pé, iye ọdún tí ó bá lè fi gbin ohun ọ̀gbìn sórí ilẹ̀ náà ni yóo wò láti ta ilẹ̀ náà. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe àìdára sí ara yín, ṣugbọn ẹ bẹ̀rù Ọlọrun yín; nítorí èmi ni OLUWA Ọlọrun yín. “Nítorí náà, ẹ níláti tẹ̀lé ìlànà mi, kí ẹ sì pa òfin mi mọ́, kí ẹ lè máa gbé inú ilẹ̀ náà láìséwu. Ilẹ̀ náà yóo so ọpọlọpọ èso, ẹ óo jẹ àjẹyó, ẹ óo sì máa gbé inú rẹ̀ láìséwu. “Bí ẹ bá ń wí pé, ‘Kí ni a óo jẹ ní ọdún keje bí a kò bá gbọdọ̀ gbin ohun ọ̀gbìn, tí a kò sì gbọdọ̀ kórè?’ Èmi OLUWA yóo pàṣẹ pé kí ibukun mi wà lórí yín ní ọdún kẹfa tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé ilẹ̀ yóo so èso tí yóo to yín jẹ fún ọdún mẹta. Nígbà tí ẹ bá gbin ohun ọ̀gbìn ní ọdún kẹjọ, ẹ óo tún máa rí àwọn èso tí ó ti wà ní ìpamọ́ jẹ títí tí yóo fi di ọdún kẹsan-an, tí ilẹ̀ yóo tún mú èso rẹ̀ jáde wá, àwọn èso ti àtẹ̀yìnwá ni ẹ óo máa jẹ. “Ẹ kò gbọdọ̀ ta ilẹ̀ kan títí ayé, nítorí pé èmi OLUWA ni mo ni gbogbo ilẹ̀, ati pé àlejò ati àtìpó ni ẹ jẹ́ fún mi. “Ninu gbogbo ilẹ̀ tí ó wà ní ìkáwọ́ yín, ẹ gbọdọ̀ fi ààyè sílẹ̀ fún ẹni tí ó bá fẹ́ ra ilẹ̀ pada. Bí arakunrin rẹ bá di aláìní tí ó bá sì tà ninu ilẹ̀ rẹ̀, ọ̀kan ninu àwọn ẹbí rẹ̀ yóo dìde láti ra ohun tí ìbátan rẹ̀ tà pada. Bí ẹni náà kò bá ní ẹbí tí ó lè ra ilẹ̀ náà pada, ṣugbọn ní ọjọ́ iwájú, tí nǹkan bá ń lọ déédé fún un, tí ó sì ní agbára láti ra ilẹ̀ náà pada, kí ó ṣírò iye ọdún tí ó ti tà á, kí ó sì san iye owó tí ó bá kù pada fún ẹni tí ó ta ilẹ̀ náà fún, lẹ́yìn náà kí ó pada sórí ilẹ̀ rẹ̀. Ṣugbọn bí kò bá ní agbára tó láti ra ilẹ̀ náà pada fúnra rẹ̀, ilẹ̀ náà yóo wà ní ọwọ́ ẹni tí ó rà á lọ́wọ́ rẹ̀ títí di ọdún jubili. Ní ọdún jubili, ẹni tí ó ra ilẹ̀ náà yóo dá a pada, ẹni tí ó ni ín yóo sì pada sórí ilẹ̀ rẹ̀. “Bí ẹnìkan bá ta ilé kan ninu ìlú olódi, ó lè rà á pada láàrin ọdún kan lẹ́yìn tí ó ti tà á. Bí ẹni náà kò bá ra ilé náà pada láàrin ọdún kan, ilé yóo di ti ẹni tí ó rà á títí lae ati ti arọmọdọmọ rẹ̀; kò ní jọ̀wọ́ rẹ̀ sílẹ̀ bí ọdún jubili tilẹ̀ dé. Ṣugbọn a óo ka àwọn ilé tí wọ́n wà ní àwọn ìlú tí kò ní odi pọ̀ mọ́ ilẹ̀ tí wọ́n kọ́ wọn lé lórí. Ẹni tí ó ta ilẹ̀ lé rà wọ́n pada, ẹni tí ó rà á sì níláti jọ̀wọ́ wọn sílẹ̀ nígbà tí ọdún jubili bá dé. Ṣugbọn àwọn ọmọ Lefi lè ra gbogbo àwọn ilé tí wọ́n wà ní ààrin ìlú wọn pada nígbàkúùgbà. Ṣugbọn bí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Lefi kò bá lo ẹ̀tọ́ ìràpadà yìí, ẹni tí ó bá ra ilé náà lọ́wọ́ rẹ̀ ninu ìlú olódi, yóo jọ̀wọ́ ilé náà sílẹ̀ ní ọdún jubili, nítorí pé, àwọn ilé tí ó wà ní ìlú àwọn ọmọ Lefi jẹ́ ìní tiwọn láàrin àwọn eniyan Israẹli. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ta ilẹ̀ tí ó jẹ́ ti gbogbogbòò, tí ó wà ní àyíká àwọn ìlú wọn, nítorí pé, ogún tiwọn nìyí títí ayérayé. “Bí arakunrin rẹ bá di aláìní tóbẹ́ẹ̀ tí kò lè bọ́ ara rẹ̀ mọ́, o níláti máa bọ́ ọ, kí ó sì máa gbé ọ̀dọ̀ rẹ, gẹ́gẹ́ bí àlejò ati àjèjì. O kò gbọdọ̀ gba èlé lọ́wọ́ rẹ̀, ṣugbọn bẹ̀rù Ọlọrun rẹ, kí o sì jẹ́ kí arakunrin rẹ máa bá ọ gbé. O kò gbọdọ̀ yá a ní owó kí o gba èlé, o kò sì gbọdọ̀ fún un ní oúnjẹ kí o gba èrè. Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ, tí ó mú ọ jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti, láti fi ilẹ̀ Kenaani fún ọ ati láti jẹ́ Ọlọrun rẹ. “Bí arakunrin rẹ, tí ń gbé tòsí rẹ bá di aláìní, tí ó sì ta ara rẹ̀ fún ọ, o kò gbọdọ̀ mú un sìn bí ẹrú. Jẹ́ kí ó wà lọ́dọ̀ rẹ bí alágbàṣe tabi bí àlejò; kí ó máa ṣiṣẹ́ fún ọ títí di ọdún jubili. Nígbà náà ni yóo kúrò lọ́dọ̀ rẹ, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀, yóo pada sí ọ̀dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀, ati sórí ilẹ̀ ìní àwọn baba rẹ̀. Nítorí pé, iranṣẹ mi ni wọ́n, tí mo kó jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti, ẹnìkan kò gbọdọ̀ tà wọ́n lẹ́rú. O kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ líle mú un, ṣugbọn bẹ̀rù Ọlọrun rẹ. Láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n yí yín ká ni ẹ ti lè ra ẹrukunrin tabi ẹrubinrin. Ẹ sì lè rà láàrin àwọn àlejò tí wọ́n wà láàrin yín ati àwọn ìdílé wọn tí wọ́n wà pẹlu yín, tí wọ́n bí ní ilẹ̀ yín, wọ́n lè di tiyín. Ẹ lè fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn ọmọ yín nígbà tí ẹ bá kú, kí wọn lè jogún wọn títí lae. Wọ́n lè di ẹrú yín, ṣugbọn ẹ̀yin ọmọ Israẹli tí ẹ jẹ́ arakunrin ara yín, ẹ kò gbọdọ̀ mú ara yín sìn, ẹ kò sì gbọdọ̀ fi ọwọ́ líle mú ara yín. “Bí àlejò tí ó wà láàrin yín bá di ọlọ́rọ̀ tí arakunrin rẹ̀ tí ó jẹ́ aládùúgbò rẹ̀ sì di aláìní, tí ó sì ta ara rẹ̀ fún àlejò náà, tabi fún ọ̀kan ninu ìdílé àlejò yín, lẹ́yìn tí ó bá ti ta ara rẹ̀, wọ́n lè rà á pada: ọ̀kan ninu àwọn arakunrin rẹ̀ lè rà á pada. Arakunrin baba tabi ìyá rẹ̀, tabi ọ̀kan ninu àwọn ìbátan rẹ̀ tabi ẹnìkan ninu àwọn ẹbí rẹ̀ le rà á pada. Bí òun pàápàá bá sì di ọlọ́rọ̀, ó lè ra ara rẹ̀ pada. Kí òun ati ẹni tí ó rà á jọ ṣírò iye ọdún tí ó fi ta ara rẹ̀, láti ọdún tí ó ti ta ara rẹ̀ fún un títí di ọdún jubili. Iye ọdún tí ó bá kù ni wọn yóo fi ṣírò owó ìràpadà rẹ̀. Wọn yóo ṣírò àkókò tí ó ti lò lọ́dọ̀ olówó rẹ̀ bí àkókò tí alágbàṣe wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Bí iye ọdún tí ó kù bá pọ̀, yóo ṣírò iye tí owó ìràpadà rẹ̀ kù ninu iye tí wọ́n san lórí rẹ̀, yóo sì san án pada. Bí ọdún tí ó kù tí ọdún jubili yóo fi pé kò bá pọ̀ mọ́, wọn yóo jọ ṣírò iye ọdún tí ó kù fún un láti fi sìn ín, òun ni yóo sì fi ṣírò owó ìràpadà rẹ̀ tí ó kù tí yóo san. Ọkunrin tí ó ta ara rẹ̀ yìí yóo dàbí iranṣẹ tí à ń gbà lọdọọdun sí ẹni tí ó rà á; ẹni tí ó rà á kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ líle mú un lójú rẹ̀. Bí ẹnikẹ́ni kò bá ra ẹni náà pada lọ́nà tí a ti là sílẹ̀ wọnyi, wọ́n gbọdọ̀ dá òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ sílẹ̀ nígbà tí ó bá di ọdún jubili. Nítorí pé, iranṣẹ mi ni àwọn ọmọ Israẹli jẹ́, iranṣẹ mi tí mo kó jáde láti ilẹ̀ Ijipti ni wọ́n. Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ. “Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe oriṣa-koriṣa kan fún ara yín, tabi kí ẹ gbé ère gbígbẹ́ kalẹ̀, tabi kí ẹ ri ọ̀wọ̀n òkúta gbígbẹ́ mọ́lẹ̀, kí ẹ sì máa bọ wọ́n, ní gbogbo ilẹ̀ yín, nítorí pé èmi ni OLUWA Ọlọrun yín. Ẹ máa pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, kí ẹ sì máa bọ̀wọ̀ fún ibi mímọ́ mi. Èmi ni OLUWA. “Bí ẹ bá ń tẹ̀lé ìlànà mi, tí ẹ sì ń pa àwọn òfin mi mọ́, n óo mú kí òjò rọ̀ ní àkókò rẹ̀, ilẹ̀ yóo mú ìbísí rẹ̀ wá, àwọn igi inú oko yóo sì máa so èso. Ẹ óo máa pa ọkà títí tí èso àjàrà yóo fi tó ká, ẹ óo sì máa ká èso àjàrà lọ́wọ́, títí àwọn nǹkan oko yóo fi tó gbìn. Ẹ óo jẹ, ẹ óo yó, ẹ óo sì máa gbé inú ilẹ̀ yín láìléwu. “N óo fun yín ní alaafia ní ilẹ̀ náà, ẹ óo dùbúlẹ̀, kò sí ẹnìkan tí yóo sì dẹ́rùbà yín. N óo lé àwọn ẹranko burúkú kúrò ní ilẹ̀ náà, ogun kò sì ní jà ní ilẹ̀ náà. Ẹ óo lé àwọn ọ̀tá yín jáde, ẹ óo sì máa fi idà pa wọ́n. Marun-un ninu yín yóo lé ọgọrun-un ọ̀tá sẹ́yìn, ọgọrun-un ninu yín yóo sì lé ẹgbaarun (10,000) àwọn ọ̀tá yín sẹ́yìn, idà ni ẹ óo fi máa pa wọ́n. N óo fi ojurere wò yín, n óo mú kí ẹ máa bímọlémọ, kí ẹ sì pọ̀ sí i, n óo sì fi ìdí majẹmu mi múlẹ̀ pẹlu yín. Ẹ óo jẹ àwọn nǹkan oko tí ẹ kó sí inú abà fún ọjọ́ pípẹ́, ẹ óo sì máa ru ìyókù wọn dànù kí ẹ lè rí ààyè kó tuntun sí. N óo fi ààrin yín ṣe ibùgbé mi, ọkàn mi kò sì ní kórìíra yín. N óo máa rìn láàrin yín, n óo jẹ́ Ọlọrun yín, ẹ óo sì jẹ́ eniyan mi. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó ko yín jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti, kí ẹ má baà ṣe ẹrú wọn mọ́. Mo ti dá igi ìdè àjàgà yín kí ẹ lè máa rìn lóòró gangan. “Ṣugbọn tí ẹ bá kọ̀, tí ẹ kò gbọ́ tèmi, tí ẹ kò sì pa gbogbo àwọn òfin mi mọ́, bí ẹ bá Pẹ̀gàn àwọn ìlànà mi, tí ọkàn yín sì kórìíra ìdájọ́ mi, tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ kọ̀ láti pa àwọn òfin mi mọ́, tí ẹ̀ ń ba majẹmu mi jẹ́, ohun tí n óo ṣe sí yín nìyí: n óo rán ìbẹ̀rù si yín lójijì, àìsàn burúkú ati ibà tí ń bani lójú jẹ́ yóo bẹ́ sílẹ̀ láàrin yín, ẹ óo sì bẹ̀rẹ̀ sí kú sára. Bí ẹ bá gbin ohun ọ̀gbìn, òfò ni yóo jásí, nítorí pé àwọn ọ̀tá yín ni yóo jẹ ẹ́. N óo kẹ̀yìn sí yín, àwọn ọ̀tá yín yóo sì ṣẹgun yín. Àwọn tí ẹ kórìíra ni yóo máa jọba lórí yín, ẹ óo sì máa sá nígbà tí ẹnikẹ́ni kò le yín. “Bí mo bá ṣe gbogbo èyí, sibẹ tí ẹ kò gbọ́ tèmi, n óo jẹ yín níyà ní ìlọ́po meje, fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín. Pẹlu gbogbo agbára tí ẹ ní, n óo tẹ̀ yín lórí ba; òjò yóo kọ̀, kò ní rọ̀, ilẹ̀ yóo sì le bí àpáta. Iṣẹ́ àṣedànù ni ẹ óo máa ṣe, nítorí pé, ilẹ̀ kò ní mú ìbísí rẹ̀ wá, àwọn igi oko kò ní so. “Bí ẹ bá lòdì sí mi, tí ẹ kò sì gbọ́ tèmi, n óo jẹ yín níyà ní ìlọ́po meje, fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín. N óo da àwọn ẹranko burúkú sáàrin yín, tí yóo máa gbé yín lọ́mọ lọ, wọn yóo run àwọn ẹran ọ̀sìn yín, n óo dín yín kù, tí yóo fi jẹ́ pé ilẹ̀ yín yóo di ahoro. “Lẹ́yìn gbogbo èyí, bí ẹ ba kọ̀, ti ẹ kò yipada, ṣugbọn tí ẹ kẹ̀yìn sí mi, èmi gan-an yóo wá kẹ̀yìn si yín, n óo sì jẹ yín níyà ní ìlọ́po meje, fún ẹ̀ṣẹ̀ yín. N óo fi ogun ko yín, tí yóo gbẹ̀san nítorí majẹmu mi. Bí ẹ bá sì kó ara yín jọ sinu àwọn ìlú olódi yín, n óo rán àjàkálẹ̀ àrùn sí ààrin yín, n óo sì fi yín lé àwọn ọ̀tá yín lọ́wọ́. Nígbà tí mo bá gba oúnjẹ lẹ́nu yín, obinrin mẹ́wàá ni yóo máa jókòó nídìí ẹyọ ààrò kan ṣoṣo láti ṣe burẹdi. Wíwọ̀n ni wọn yóo máa wọn oúnjẹ le yín lọ́wọ́; ẹ óo jẹ, ṣugbọn ẹ kò ní yó. “Bí mo bá ṣe gbogbo èyí, tí ẹ kò sì gbọ́ tèmi, ṣugbọn tí ẹ tún kẹ̀yìn sí mi, n óo fi ibinu kẹ̀yìn sí yín, n óo sì jẹ yín níyà fúnra mi, nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín. Ebi yóo pa yín tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ óo máa pa àwọn ọmọ yín jẹ. N óo wó àwọn ilé ìsìn yín gbogbo tí wọ́n wà lórí òkè, n óo wó àwọn pẹpẹ turari yín lulẹ̀; n óo kó òkú yín dà sórí àwọn oriṣa yín, ọkàn mi yóo sì kórìíra yín. N óo sọ àwọn ìlú yín di ahoro, àwọn ilé ìsìn yín yóo sì ṣófo, n kò ní gba ẹbọ yín mọ́. N óo run ilẹ̀ yín, tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnu yóo fi ya àwọn ọ̀tá yín, tí wọn yóo pada wá tẹ̀dó ninu rẹ̀. N óo fọ́n yín káàkiri ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, idà ni wọn yóo máa fi pa yín ní ìpakúpa, ilẹ̀ yín ati àwọn ìlú yín yóo di ahoro. Nígbà tí ẹ bá wà ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín, ilẹ̀ ti ẹ̀yin pàápàá yóo wá ní ìsinmi, níwọ̀n ìgbà tí ó bá wà ní ahoro, ilẹ̀ yín yóo gbádùn ìsinmi rẹ̀. Nígbà tí ó bá wà ní ahoro, yóo ní irú ìsinmi tí kò ní rí ni àkókò ìsinmi yín, nígbà tí ẹ̀ ń gbé inú rẹ̀. “Ìwọ̀nba àwọn tí wọ́n bá kù, n óo da jìnnìjìnnì bo ọkàn wọn ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín, tóbẹ́ẹ̀ tí ìró ewé tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lásán yóo máa lé wọn sá; wọn yóo sì máa sá àsá-dojúbolẹ̀ bí ẹni pé ogun ní ń lé wọn. Wọn yóo máa ṣubú nígbà tí ẹnikẹ́ni kò lé wọn. Wọn yóo máa ṣubú lórí ara wọn bí ẹni tí ogun ń lé lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ń lé wọn. Kò sì ní sí agbára fun yín láti dúró níwájú àwọn ọ̀tá yín. Ẹ óo parun láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín yóo sì gbé yín mì. Ìwọ̀nba ẹ̀yin tí ẹ bá ṣẹ́kù, kíkú ni ẹ óo máa kú sára lórí ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín, nítorí àìdára yín ati ti àwọn baba yín. “Ṣugbọn bí wọn bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ati ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wọn, nípa ìwà ọ̀dàlẹ̀ tí wọ́n hù sí mi, ati lílòdì tí wọ́n lòdì sí mi, tí mo fi kẹ̀yìn sí wọn, tí mo fi mú wọn wá sí ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn; bí ọkàn wọn tí ó ti yigbì tẹ́lẹ̀ bá rọ̀, tí wọ́n bá sì ṣe àtúnṣe fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn, n óo ranti majẹmu tí mo bá Jakọbu, ati Isaaki, ati Abrahamu dá, n óo sì ranti ilẹ̀ náà. Ṣugbọn wọn yóo jáde kúrò ninu ilẹ̀ náà, ilẹ̀ náà yóo sì ní ìsinmi nígbà ti ó bá wà ní ahoro, nígbà tí wọn kò bá sí níbẹ̀. Wọ́n gbọdọ̀ gba ìjẹníyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nítorí pé, wọ́n kẹ́gàn ìdájọ́ mi, wọ́n sì kórìíra ìlànà mi. Sibẹsibẹ nígbà tí wọ́n bá wà ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn, n kò ní ṣàì náání wọn; bẹ́ẹ̀ ni n kò ní kórìíra wọn débi pé kí n pa wọ́n run patapata, kí n sì yẹ majẹmu mi pẹlu wọn, nítorí èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn. Ṣugbọn n óo tìtorí tiwọn ranti majẹmu tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá, àní àwọn tí mo kó jáde láti ilẹ̀ Ijipti lójú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, kí n lè jẹ́ Ọlọrun wọn. Èmi ni OLUWA.” Àwọn ni ìlànà ati òfin tí OLUWA fi lélẹ̀ láàrin òun ati àwọn ọmọ Israẹli, láti ọwọ́ Mose. OLUWA sọ fun Mose pé kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Bí ẹnìkan bá jẹ́jẹ̀ẹ́ pataki kan láti fi odidi eniyan fún OLUWA, tí kò bá lè mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣẹ, iye tí ó níláti san nìyí: Fún ọkunrin tí ó jẹ́ ẹni ogún ọdún sí ọgọta ọdún, yóo san aadọta ìwọ̀n ṣekeli fadaka. Ìwọ̀n ṣekeli ibi mímọ́ ni kí wọ́n fi wọn owó náà. Bí ó bá jẹ́ obinrin ni, ẹni náà yóo san ọgbọ̀n ìwọ̀n ṣekeli. Bí ó bá jẹ́ ọkunrin, tí ó jẹ́ ẹni ọdún marun-un sí ogun ọdún, yóo san ogun ìwọ̀n ṣekeli; bí ó bá jẹ́ obinrin, yóo san ṣekeli mẹ́wàá. Bí ó bá jẹ́ ọmọ oṣù kan sí ọmọ ọdún marun-un, tí ó sì jẹ́ ọkunrin, yóo san ìwọ̀n ṣekeli fadaka marun-un, bí ó bá jẹ́ obinrin, yóo san ìwọ̀n ṣekeli fadaka mẹta. Bí ẹni náà bá tó ẹni ọgọta ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí ó bá jẹ́ ọkunrin, kí ó san ṣekeli mẹẹdogun, ṣugbọn bí ó bá jẹ́ obinrin, kí ó san Ṣekeli mẹ́wàá. “Bí ẹni náà bá jẹ́ talaka tóbẹ́ẹ̀ tí kò lè san iye tí ó yẹ kí ó san, mú ẹni tí ó fi jẹ́jẹ̀ẹ́ wá sí ọ̀dọ̀ alufaa kí alufaa díye lé e gẹ́gẹ́ bí agbára ẹni tí ó jẹ́jẹ̀ẹ́ yìí. “Bí ó bá jẹ́ pé ẹran ni eniyan jẹ́jẹ̀ẹ́ láti mú wá, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sí OLUWA, gbogbo irú nǹkan bẹ́ẹ̀ tí eniyan bá fún OLUWA jẹ́ mímọ́. Kò gbọdọ̀ fi ohunkohun dípò rẹ̀, tabi kí ó pààrọ̀ rẹ̀. Kò gbọdọ̀ pààrọ̀ ẹran tí kò dára sí èyí tí ó dára, tabi kí ó pààrọ̀ èyí tí ó dára sí èyí tí kò dára. Bí ó bá jẹ́ pé ó fẹ́ fi ẹran kan pààrọ̀ ẹran mìíràn, ati èyí tí wọ́n pààrọ̀, ati èyí tí wọ́n fẹ́ fi pààrọ̀ rẹ̀, wọ́n di mímọ́. Bí ó bá jẹ́ ẹran tí kò mọ́ ni, tí eniyan kò lè fi rúbọ sí OLUWA, kí ẹni náà mú ẹran náà tọ alufaa wá, kí alufaa wò ó bóyá ó dára tabi kò dára; iye tí alufaa bá pè é náà ni iye rẹ̀. Ṣugbọn bí ẹni náà bá fẹ́ ra ẹran náà pada, yóo fi ìdámárùn-ún kún iye owó rẹ̀. “Nígbà tí ẹnìkan bá ya ilé rẹ̀ sọ́tọ̀ fún OLUWA, alufaa yóo wò ó bóyá ó dára tabi kò dára; iyekíye tí alufaa bá pè é ni iye rẹ̀. Bí ẹni tí ó ya ilé yìí sọ́tọ̀ fún OLUWA bá fẹ́ rà á pada, yóo san iye tí ilé náà bá tó, yóo sì tún fi ìdámárùn-ún iye owó rẹ̀ lé e. Nígbà tí ó bá san owó ilé náà pada, ilé yóo di tirẹ̀. “Bí ẹnìkan bá ya apá kan ninu ilẹ̀ tí ó jogún sọ́tọ̀ fún OLUWA, ìwọ̀n èso tí eniyan bá lè rí ká lórí ilẹ̀ náà ni wọn yóo fi díye lé e. Bí a bá lè rí ìwọ̀n Homeri baali kan ká ninu rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, iye rẹ̀ yóo jẹ́ aadọta ìwọ̀n ṣekeli fadaka. Bí ó bá jẹ́ pé láti ọdún jubili ni ó ti ya ilẹ̀ náà sọ́tọ̀ fún OLUWA, iyekíye tí ilẹ̀ náà bá tó lójú yín kò gbọdọ̀ dín. Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé lẹ́yìn ọdún Jubili ni ó ya ilẹ̀ rẹ̀ sọ́tọ̀ fún OLUWA, alufaa yóo ṣírò iye tí ó tó, gẹ́gẹ́ bí iye ọdún tí ó kù kí ọdún Jubili mìíràn pé bá ti pẹ́ sí, ẹ óo ṣí iye owó ọdún tí ó dínkù kúrò lára iye ilẹ̀ náà. Bí ẹni tí ó ya ilẹ̀ náà sọ́tọ̀ fún OLUWA bá fẹ́ rà á pada, yóo san iye tí ó bá tó, yóo sì fi ìdámárùn-ún owó rẹ̀ lé e, ilẹ̀ náà yóo sì di tirẹ̀. Ṣugbọn bí kò bá fẹ́ ra ilẹ̀ náà pada, tabi ti ó bá ti ta ilẹ̀ náà fún ẹlòmíràn, kò ní ẹ̀tọ́ láti rà á pada mọ́. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n bá jọ̀wọ́ ilẹ̀ náà ní ọdún Jubili, ó níláti jẹ́ mímọ́ fún OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ tí wọ́n ti fi fún OLUWA; yóo sì di ohun ìní alufaa. “Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé rírà ni ó ra ilẹ̀ tí ó yà sọ́tọ̀ fún OLUWA, tí kì í ṣe apá kan ninu ilẹ̀ àjogúnbá tirẹ̀, alufaa yóo ṣírò iye tí ilẹ̀ náà bá tó títí di ọdún Jubili, ẹni náà yóo sì san iye rẹ̀ ní ọjọ́ náà bí ohun ìyàsọ́tọ̀ fún OLUWA. Nígbà tí ó bá di ọdún Jubili, ilẹ̀ yìí yóo pada di ti ẹni tí wọ́n rà á lọ́wọ́ rẹ̀, tí ilẹ̀ yìí jẹ́ ilẹ̀ àjogúnbá rẹ̀ láàárọ̀ ọjọ́. “Ìwọ̀n ṣekeli tí wọn ń lò ninu ibi mímọ́ ni kí ẹ máa lò láti wọn ohun gbogbo: Ogún ìwọ̀n gera ni yóo jẹ́ ìwọ̀n ṣekeli kan. “Ṣugbọn gbogbo ẹran tí ó bá ti jẹ́ àkọ́bí, ti OLUWA ni, ẹnikẹ́ni kò ṣẹ̀ṣẹ̀ tún ní yà á sọ́tọ̀ mọ́; kì báà jẹ́ mààlúù tabi aguntan, ti OLUWA ni. Bí ó bá jẹ́ ẹran tí kò mọ́, kí ó san owó rẹ̀ pada gẹ́gẹ́ bí iye tí ẹ bá dá lé e, kí ó sì fi ìdámárùn-ún owó náà lé e. Bí ẹni tí ó ni í kò bá sì rà á pada, kí wọ́n tà á ní iyekíye tí ẹ bá dá lé e. “Ṣugbọn ohunkohun tí eniyan bá ti fi fún OLUWA, kì báà jẹ́ eniyan ni, tabi ẹranko, tabi ilẹ̀ àjogúnbá rẹ̀, yóo jẹ́ títà tabi kí ó rà á pada. Ohunkohun tí a bá ti fi fún OLUWA, ó di mímọ́ jùlọ fún OLUWA. Ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá yà sọ́tọ̀ pé ó gbọdọ̀ jẹ́ pípa láàrin àwọn eniyan, ẹnìkan kò gbọdọ̀ rà á pada, pípa ni wọ́n gbọdọ̀ pa á. “Gbogbo ìdámẹ́wàá ilẹ̀ náà, kì báà jẹ́ ti èso ilẹ̀, tabi ti èso igi, ti OLUWA ni; mímọ́ ni fún OLUWA. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ra ìdámẹ́wàá rẹ̀ pada, ó níláti fi ìdámárùn-ún ìdámẹ́wàá yìí lé e. Ìdámẹ́wàá gbogbo agbo mààlúù, ati ti agbo aguntan jẹ́ ti OLUWA. Bí ẹran mẹ́wàá bá kọjá lábẹ́ ọ̀pá darandaran, ikẹwaa gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún OLUWA. Darandaran náà kò gbọdọ̀ bèèrè bóyá ó dára tabi kò dára, bẹ́ẹ̀ ni kò sì gbọdọ̀ pààrọ̀ rẹ̀. Bí ó bá fẹ́ pààrọ̀ rẹ̀, ati èyí tí ó fi pààrọ̀ ati èyí tí ó pààrọ̀, mejeeji jẹ́ mímọ́ fún OLUWA, ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ rà á pada.” Àwọn òfin tí a ti kà sílẹ̀ wọnyi ni OLUWA fún Mose lórí Òkè Sinai fún àwọn ọmọ Israẹli. Ní ọjọ́ kinni oṣù keji, ní ọdún keji tí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, OLUWA sọ fún Mose ninu Àgọ́ Àjọ, tí ó wà ninu aṣálẹ̀ Sinai, pé, “Ẹ ka iye àwọn ọmọ Israẹli, ní agbo-ilé agbo-ilé, ati ìdílé-ìdílé; kí ẹ sì kọ orúkọ gbogbo àwọn ọkunrin sílẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. Ìwọ ati Aaroni, ẹ ka gbogbo àwọn tí wọ́n lè jáde lọ sí ojú ogun, láti ẹni ogún ọdún lọ sókè. Ẹ kà wọ́n ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, ati ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Kí ọkunrin kọ̀ọ̀kan, láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan wà pẹlu yín láti máa ràn yín lọ́wọ́. Àwọn ọkunrin tí yóo máa ràn yín lọ́wọ́ gbọdọ̀ jẹ́ baálẹ̀ ní àdúgbò wọn.” Orúkọ àwọn baálẹ̀-baálẹ̀ náà nìwọ̀nyí: Elisuri ọmọ Ṣedeuri ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Reubẹni. Ṣelumieli ọmọ Suriṣadai ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Simeoni. Naṣoni ọmọ Aminadabu ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Juda. Netaneli ọmọ Suari ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Isakari. Eliabu ọmọ Heloni ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Sebuluni. Ninu àwọn ọmọ Josẹfu, Eliṣama ọmọ Amihudu ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Efuraimu; Gamalieli ọmọ Pedasuri ni yóo sì jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Manase. Abidani ọmọ Gideoni ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini. Ahieseri ọmọ Amiṣadai ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Dani. Pagieli ọmọ Okirani ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Aṣeri. Eliasafu ọmọ Deueli ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Gadi. Ahira ọmọ Enani ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Nafutali. Àwọn ni olórí tí a yàn ninu àwọn ọmọ Israẹli, olukuluku wọn jẹ́ olórí ninu ẹ̀yà wọn, ati ní ìdílé wọn. Mose ati Aaroni pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ ní ọjọ́ kinni oṣù keji, pẹlu ìrànlọ́wọ́ àwọn ọkunrin mejila náà, wọ́n kọ orúkọ gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sílẹ̀, láti ẹni ogún ọdún sókè, ní agbo-ilé agbo-ilé, ati ní ìdílé-ìdílé. Mose kà wọ́n ní ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu aṣálẹ̀ Sinai gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un. Ninu ẹ̀yà Reubẹni, tíí ṣe àkọ́bí Israẹli, àwọn tí wọ́n jẹ́ ẹni ogún ọdún sókè, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé jẹ́ ẹgbaa mẹtalelogun ó lé ẹẹdẹgbẹta (46,500). Ninu ẹ̀yà Simeoni, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé jẹ́ ẹgbaa mọkandinlọgbọn ó lé eedegbeje (59,300). Ninu ẹ̀yà Gadi, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé jẹ́ ẹgbaa mejilelogun ó lé aadọta lé ní ẹgbẹjọ (45,650). Ninu ẹ̀yà Juda, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé jẹ́ ẹgbaa mẹtadinlogoji ó lé ẹgbẹta (74,600). Ninu ẹ̀yà Isakari, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé jẹ́ ẹgbaa mẹtadinlọgbọn ó lé irinwo (54,400). Ninu ẹ̀yà Sebuluni, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé jẹ́ ẹgbaa mejidinlọgbọn ó lé egbeje (57,400). Ninu ẹ̀yà Efuraimu àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (40,500). Ninu ẹ̀yà Manase, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé jẹ́ ẹgbaa mẹrindinlogun ó lé igba (32,200). Ninu ẹ̀yà Bẹnjamini, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé jẹ́ ẹgbaa mẹtadinlogun ó lé egbeje (35,400). Ninu ẹ̀yà Dani, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé jẹ́ ẹgbaa mọkanlelọgbọn ó lé ẹẹdẹgbẹrin (62,700). Ninu ẹ̀yà Aṣeri, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé jẹ́ ọ̀kẹ́ meji le ẹẹdẹgbẹjọ (41,500). Ninu ẹ̀yà Nafutali àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé jẹ́ ẹgbaa mẹrindinlọgbọn ó lé egbeje (53,400). Àwọn ni àwọn tí Mose ati Aaroni kà pẹlu ìrànlọ́wọ́ àwọn olórí mejila tí a yàn láti inú àwọn ẹ̀yà Israẹli. Àròpọ̀ iye àwọn ọmọ Israẹli, ní ìdílé-ìdílé, láti ẹni ogún ọdún sókè, àwọn tí wọ́n lè lọ sójú ogun, jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ eniyan o le egbejidinlogun ó dín aadọta (603,550). Ṣugbọn wọn kò ka àwọn ọmọ Lefi mọ́ wọn, nítorí pé OLUWA ti sọ fún Mose pé, kí ó má ka ẹ̀yà Lefi mọ́ àwọn ọmọ Israẹli nígbà tí ó bá ń kà wọ́n. Ṣugbọn kí ó fi wọ́n ṣe alákòóso Àgọ́ Ẹ̀rí ati àwọn ohun èlò tí ó wà ninu rẹ̀. Àwọn ni yóo máa ru Àgọ́ náà ati gbogbo ohun èlò tí ó wà ninu rẹ̀, wọn yóo sì máa ṣe iṣẹ́ ìsìn níbẹ̀. Wọ́n óo pa ibùdó wọn yí Àgọ́ náà ká. OLUWA ní, “Nígbà tí ẹ bá fẹ́ ṣí lọ siwaju, kí àwọn ọmọ Lefi tú Àgọ́ Ẹ̀rí palẹ̀ kí wọ́n rù ú. Nígbà tí ẹ bá sì dúró, àwọn ọmọ Lefi ni kí wọn pa Àgọ́ náà. Bí ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe ọmọ Lefi bá súnmọ́ tòsí wọn, pípa ni kí wọ́n pa á. Kí àwọn ọmọ Israẹli yòókù pa àgọ́ wọn ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, olukuluku ní ibùdó rẹ̀, lábẹ́ àsíá ẹ̀yà rẹ̀. Ṣugbọn àwọn ọmọ Lefi ni kí wọ́n pàgọ́ yí Àgọ́-Ẹ̀rí ká, kí àwọn tí kì í ṣe ọmọ Lefi má baà súnmọ́ Àgọ́ náà, kí n má baà bínú sí àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ọmọ Lefi ni yóo máa ṣe ìtọ́jú Àgọ́ Ẹ̀rí náà.” Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún Mose. OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé: Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli yóo bá pàgọ́ wọn, kí olukuluku máa pàgọ́ rẹ̀ lábẹ́ àsíá ẹ̀yà rẹ̀, ati lábẹ́ ọ̀págun ìdílé rẹ̀. Kí wọ́n máa pàgọ́ wọn yí Àgọ́ náà ká. Kí àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ àsíá ẹ̀yà Juda máa pàgọ́ wọn sí ìhà ìlà oòrùn ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí; Naṣoni ọmọ Aminadabu ni yóo jẹ́ olórí wọn. Àwọn ọmọ ogun tí a kà ninu wọn jẹ́ ẹgbaa mẹtadinlogoji ó lé ẹgbẹta (74,600). Kí ẹ̀yà Isakari pàgọ́ tẹ̀lé ẹ̀yà Juda; Netaneli ọmọ Suari ni yóo jẹ́ olórí wọn. Àwọn ọmọ ogun tí a kà ninu wọn jẹ́ ẹgbaa mẹtadinlọgbọn ó lé irinwo (54,400). Kí ẹ̀yà Sebuluni pàgọ́ tẹ̀lé ẹ̀yà Isakari. Eliabu ọmọ Heloni ni yóo jẹ́ olórí wọn. Àwọn ọmọ ogun tí a kà ninu wọn jẹ́ ẹgbaa mejidinlọgbọn ó lé egbeje (57,400). Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ibùdó Juda jẹ́ ẹgbaa mẹtalelaadọrun-un ó lé irinwo (186,400). Àwọn ni yóo máa ṣáájú nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli bá fẹ́ kó kúrò ní ibùdó kan lọ sí ibòmíràn. Àsíá ibùdó ẹ̀yà Reubẹni yóo máa wà ní ìhà gúsù ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí; Elisuri ọmọ Ṣedeuri ni yóo jẹ́ olórí wọn. Àwọn ọmọ ogun tí a kà ninu wọ́n jẹ́ ẹgbaa mẹtalelogun ó lé ẹẹdẹgbẹta (46,500). Ẹ̀yà Simeoni ni yóo pàgọ́ tẹ̀lé ẹ̀yà Reubẹni; Ṣelumieli ọmọ Suriṣadai ni yóo jẹ́ olórí wọn. Àwọn ọmọ ogun tí a kà ninu wọ́n jẹ́ ẹgbaa mọkandinlọgbọn ó lé eedegbeje (59,300). Ẹ̀yà Gadi ni yóo pàgọ́ tẹ̀lé ẹ̀yà Simeoni; Eliasafu ọmọ Reueli ni yóo jẹ́ olórí wọn. Àwọn ọmọ ogun tí a kà ninu wọ́n jẹ́ ẹgbaa mejilelogun ó lé aadọta lé ní ẹgbẹjọ (45,650). Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ibùdó Reubẹni jẹ́ ẹgbaa marundinlọgọrin ó lé aadọta lé ní egbeje (151,450). Àwọn ni yóo máa tẹ̀lé ibùdó Juda nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli bá fẹ́ kó kúrò ní ibùdó kan lọ sí ibòmíràn. Lẹ́yìn náà, Àgọ́ Ẹ̀rí yóo ṣí, pẹlu àgọ́ àwọn ọmọ Lefi. Bí wọ́n ti pàgọ́ yí Àgọ́ náà ká, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóo ṣe máa ṣí, olukuluku ní ipò rẹ̀, pẹlu àsíá ẹ̀yà rẹ̀. Àsíá ibùdó ẹ̀yà Efuraimu yóo máa wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn ní ìsọ̀rí-ìsọrí; Eliṣama ọmọ Amihudu ni yóo jẹ́ olórí wọn. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí a kà jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (40,500). Ẹ̀yà Manase ni yóo pàgọ́ tẹ̀lé ẹ̀yà Efuraimu; Gamalieli, ọmọ Pedasuri, ni yóo sì jẹ́ olórí wọn. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí a kà jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaafa ó lé igba (32,200). Ẹ̀yà Bẹnjamini ni yóo pàgọ́ tẹ̀lé ẹ̀yà Manase; Abidoni, ọmọ Gideoni ni yóo sì jẹ́ olórí wọn. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí a kà jẹ́ ẹgbaa mẹtadinlogun ó lé egbeje (35,400). Àpapọ̀ gbogbo àgọ́ Efuraimu ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí jẹ́ ọ̀kẹ́ marun-un ó lé ẹgbaarin ati ọgọrun-un (108,100). Àwọn ni wọn yóo jẹ́ ìpín kẹta tí àwọn ọmọ Israẹli bá fẹ́ ṣí láti ibùdó kan sí òmíràn. Àsíá ibùdó ẹ̀yà Dani yóo wà ní ìhà àríwá ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí; Ahieseri, ọmọ Amiṣadai, ni yóo jẹ́ olórí wọn. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí a kà jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹta ó lé ẹẹdẹgbẹsan-an (62,700). Ẹ̀yà Aṣeri ni yóo pàgọ́ tẹ̀lé ẹ̀yà Dani; Pagieli, ọmọ Okirani, ni yóo sì jẹ́ olórí wọn. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí a kà jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹẹdẹgbẹjọ (41,500). Lẹ́yìn náà ni ẹ̀yà Nafutali; Ahira, ọmọ Enani ni yóo jẹ́ olórí wọn. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí a kà jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹẹdẹgbaaje ati irinwo (53,400). Àpapọ̀ gbogbo àgọ́ Efuraimu ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, jẹ́ ọ̀kẹ́ meje ó lé ẹẹdẹgbaasan-an ati ẹgbẹta (157,600). Àwọn ni wọn yóo tò sẹ́yìn patapata. Ó jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ọmọ Israẹli tí a kà, gẹ́gẹ́ bí ìdílé baba wọn. Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní àgọ́ tí a kà ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé ẹgbẹtadinlogun ati aadọjọ (603,550). Ṣugbọn a kò ka àwọn ẹ̀yà Lefi mọ́ àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún Mose. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose, wọ́n pàgọ́ ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe tẹ̀síwájú, olukuluku wà ninu ìdílé tirẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn. Àwọn wọnyi ni ìdílé Aaroni ati ti Mose, nígbà tí OLUWA bá Mose sọ̀rọ̀ ní orí òkè Sinai. Orúkọ àwọn ọmọ Aaroni lọkunrin nìwọ̀nyí: Nadabu ni àkọ́bí, lẹ́yìn rẹ̀ ni Abihu, Eleasari ati Itamari. Àwọn ni ó ta òróró sí lórí, láti yà wọ́n sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ alufaa. Nadabu ati Abihu kú nígbà tí wọ́n fi iná tí a kò yà sí mímọ́ rúbọ sí OLUWA ninu aṣálẹ̀ Sinai. Wọn kò bímọ. Nítorí náà Eleasari ati Itamari ní ń ṣe iṣẹ́ alufaa ní ìgbà ayé Aaroni, baba wọn. OLUWA sọ fún Mose pé, “Mú ẹ̀yà Lefi wá siwaju Aaroni alufaa, kí wọ́n sì máa ṣe iranṣẹ fún un. Àwọn ni yóo máa ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún àwọn alufaa ati fún gbogbo ìjọ eniyan Israẹli níwájú Àgọ́ Àjọ bí àwọn alufaa tí ń ṣe iṣẹ́ níbi mímọ́. Àwọn ọmọ Lefi yóo máa ṣe ìtọ́jú gbogbo ohun èlò Àgọ́ Àjọ, wọn óo sì máa ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún gbogbo ọmọ Israẹli bí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ níbi mímọ́. Fi àwọn ọmọ Lefi fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀. Àwọn nìkan ni wọn óo jẹ́ iranṣẹ fún wọn láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Yan Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ láti máa ṣe iṣẹ́ alufaa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ ibi mímọ́, pípa ni kí ẹ pa á.” OLUWA sọ fún Mose pé, “Mo ti yan àwọn ọmọ Lefi láàrin àwọn eniyan Israẹli dípò àwọn àkọ́bí ọmọ Israẹli. Tèmi ni àwọn ọmọ Lefi, nítorí tèmi ni gbogbo àwọn àkọ́bí. Nígbà tí mo pa gbogbo àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Ijipti ni mo ya gbogbo àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Israẹli sọ́tọ̀; kì báà ṣe ti eniyan tabi ti ẹranko, tèmi ni gbogbo wọn. Èmi ni OLUWA.” OLUWA sọ fún Mose ninu aṣálẹ̀ Sinai, ó ní, “Ka iye àwọn ọmọkunrin Lefi gẹ́gẹ́ bí ìdílé baba wọn. Bẹ̀rẹ̀ láti ọmọ oṣù kan lọ sókè.” Mose sì kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un. Lefi ní ọmọkunrin mẹta: Geriṣoni, Kohati ati Merari, wọ́n sì jẹ́ olórí àwọn ìdílé wọn. Orúkọ àwọn ọmọ Geriṣoni ni Libini ati Ṣimei. Orúkọ àwọn ọmọ Kohati ni Amramu, Iṣari, Heburoni ati Usieli. Orúkọ àwọn ọmọ Merari ni Mahili ati Muṣi. Àwọn ìdílé Lefi nìwọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn. Geriṣoni ni baba ńlá àwọn ọmọ Libini ati àwọn ọmọ Ṣimei. Gbogbo àwọn ọkunrin tí a kà ninu wọn, láti ọmọ oṣù kan sókè jẹ́ ẹgbaarin ó dín ẹẹdẹgbẹta (7,500). Àwọn ọmọ Geriṣoni yóo pàgọ́ tiwọn sẹ́yìn Àgọ́ Àjọ ní ìhà ìwọ̀ oòrùn. Eliasafu ọmọ Laeli ni yóo jẹ́ olórí wọn. Àwọn ni yóo máa ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́ ati Àgọ́ Àjọ, aṣọ ìbòrí rẹ̀, ati aṣọ tí wọ́n ń ta sí ẹnu ọ̀nà àbáwọlé rẹ̀; aṣọ tí wọ́n ń ta sí àgbàlá, aṣọ tí wọ́n ń ta sí ẹnu ọ̀nà àbáwọ àgbàlá tí ó yí ibi mímọ́ ati pẹpẹ ká, ati okùn, ati gbogbo nǹkan tí wọ́n ń lò pẹlu rẹ̀. Kohati ni baba ńlá àwọn ọmọ Amramu ati àwọn ọmọ Iṣari, àwọn ọmọ Heburoni ati àwọn ọmọ Usieli. Gbogbo àwọn ọkunrin tí a kà ninu wọn láti ọmọ oṣù kan sókè jẹ́ ẹgbaarin ó lé ẹgbẹta (8,600). Àwọn ni wọ́n ń ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́. Àwọn ọmọ Kohati yóo pàgọ́ tiwọn sí ẹ̀gbẹ́ Àgọ́ Àjọ ní ìhà gúsù. Elisafani ọmọ Usieli ni yóo jẹ́ olórí wọn. Àwọn ni yóo máa ṣe ìtọ́jú Àpótí majẹmu ati tabili, ọ̀pá fìtílà ati àwọn pẹpẹ, ati àwọn ohun èlò ní ibi mímọ́, tí àwọn alufaa máa ń lò fún iṣẹ́ ìsìn; ati aṣọ ìbòjú, ati gbogbo iṣẹ́ tí ó jẹ mọ́ ti àwọn ohun èlò wọnyi. Eleasari ọmọ Aaroni alufaa ni yóo máa ṣe alákòóso àwọn olórí àwọn ọmọ Lefi, òun ni yóo sì máa ṣe àkóso àwọn tí ń ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́. Merari ni baba ńlá àwọn ọmọ Mahili, ati ti àwọn ọmọ Muṣi. Gbogbo àwọn ọkunrin tí a kà ninu wọn láti ọmọ oṣù kan sókè jẹ́ ẹgbaata lé igba (6,200). Surieli ọmọ Abihaili ni yóo jẹ́ olórí wọn. Kí wọ́n pàgọ́ tiwọn sí ìhà àríwá Àgọ́ Àjọ. Àwọn ni yóo máa ṣe ìtọ́jú àwọn igi àkànpọ̀ ibi mímọ́, ati àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, àwọn òpó rẹ̀ pẹlu àwọn ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀, ati gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, ati gbogbo iṣẹ́ tí ó jẹ mọ́ wọn; ati gbogbo òpó àgbàlá yíká, pẹlu àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn, èèkàn wọn, ati okùn wọn. Mose pẹlu Aaroni ati àwọn ọmọ wọn yóo pa àgọ́ tiwọn sí ìhà ìlà oòrùn, níwájú Àgọ́ Àjọ. Àwọn ni yóo máa ṣe iṣẹ́ ìsìn fún àwọn ọmọ Israẹli ní ibi mímọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ ibi mímọ́, pípa ni kí wọ́n pa á. Gbogbo àwọn ọmọ Lefi lọkunrin, láti ọmọ oṣù kan sókè tí Mose kà ní ìdílé-ìdílé, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA jẹ́ ẹgbaa mọkanla (22,000). OLUWA sọ fún Mose pé, “Ka gbogbo àkọ́bí lọkunrin láàrin àwọn ọmọ Israẹli láti ọmọ oṣù kan sókè, kí o sì kọ orúkọ wọn sílẹ̀. Gba àwọn ọmọ Lefi fún mi dípò awọn àkọ́bí ní Israẹli, sì gba àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, dípò àwọn àkọ́bí ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli. Èmi ni OLUWA.” Mose bá ka gbogbo àwọn àkọ́bí ninu àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un. Gbogbo àkọ́bí ọkunrin, gẹ́gẹ́ bí orúkọ wọn, lati ọmọ oṣù kan lọ sókè ní iye wọn, lápapọ̀, wọn jẹ́ ẹgbaa mọkanla ó lé igba ati mẹtalelaadọrin (22,273). OLUWA sọ fún Mose pé, “Gba àwọn ọmọ Lefi dípò gbogbo àwọn àkọ́bí ninu àwọn ọmọ Israẹli, ati ohun ọ̀sìn àwọn ọmọ Lefi dípò ohun ọ̀sìn wọn. Àwọn ọmọ Lefi yóo sì jẹ́ tèmi. Èmi ni OLUWA. Níwọ̀n ìgbà tí àwọn àkọ́bí Israẹli fi igba ó lé mẹtalelaadọrin (273) pọ̀ ju àwọn ọmọ Lefi lọ, wọ́n níláti rà wọ́n pada. Kí o gba ṣekeli marun-un-marun-un lórí ẹnìkọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ṣekeli tí wọn ń lò ní ibi mímọ́. Kí o sì kó owó náà fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀.” Mose gba owó ìràpadà náà lórí àwọn tí iye àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli fi pọ̀ ju àwọn ọmọ Lefi lọ. Owó tí ó gbà jẹ́ egbeje ìwọ̀n ṣekeli fadaka ó dín marundinlogoji (1,365), gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ṣekeli tí wọn ń lò ní ibi mímọ́. Mose fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ní owó ìràpadà náà gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un. OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé: “Ẹ ka iye àwọn ọmọ Kohati láàrin àwọn ọmọ Lefi, ní ìdílé-ìdílé, gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn. Kí ẹ ka àwọn ọkunrin wọn, láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé aadọta, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ. Àwọn ni yóo máa ṣe ìtọ́jú àwọn ohun mímọ́ jùlọ ninu Àgọ́ Àjọ. “Nígbà tí ẹ bá fẹ́ kó kúrò ní ibùdó kan, Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ yóo wá láti ṣí aṣọ ìbòjú tí ó wà níwájú Àpótí majẹmu, wọn yóo sì fi bo Àpótí náà. Lẹ́yìn èyí, wọn óo fi awọ dídán bò ó, wọn óo tẹ́ aṣọ aláwọ̀ aró lé e, wọn yóo sì ti ọ̀pá tí a fi ń gbé e bọ̀ ọ́. “Wọn yóo da aṣọ aláwọ̀ aró bo tabili tí burẹdi ìfihàn máa ń wà lórí rẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọn yóo kó àwọn nǹkan wọnyi lé e lórí: àwọn àwo turari, àwọn àwokòtò, ati àwọn ìgò fún ọtí ìrúbọ. Burẹdi ìfihàn sì gbọdọ̀ wà lórí rẹ̀ nígbà gbogbo. Lẹ́yìn náà, wọn yóo da aṣọ pupa ati awọ dídán bò ó. Wọn yóo sì ti igi tí a fi ń gbé e bọ̀ ọ́. “Wọn yóo fi aṣọ aláwọ̀ aró bo ọ̀pá fìtílà ati àwọn fìtílà rẹ̀ ati àwọn ohun tí à ń lò pẹlu rẹ̀ ati gbogbo ohun èlò òróró. Wọn yóo sì fi awọ dídán dì wọ́n, wọn yóo sì gbé wọn ka orí igi tí a óo fi gbé wọn. “Lẹ́yìn èyí, wọn óo da aṣọ aláwọ̀ aró bo pẹpẹ wúrà, wọn óo fi awọ ewúrẹ́ tí ń dán bò ó, wọn óo sì ti igi tí a fi ń gbé e bọ̀ ọ́. Wọn yóo di àwọn ohun èlò ìsìn yòókù sinu aṣọ aláwọ̀ aró kan, wọn yóo sì fi awọ ewúrẹ́ tí ń dán bò wọ́n, wọn óo gbé wọn ka orí igi tí a óo fi gbé wọn. Wọn óo kó eérú kúrò lórí pẹpẹ, wọn óo fi aṣọ elése àlùkò bò ó. Wọn óo kó gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀ sórí rẹ̀, àwọn àwo turari, àmúga tí a fi ń mú ẹran, ọkọ́ tí a fi ń kó eérú, àwo kòtò ati gbogbo ohun èlò tí ó jẹ mọ́ pẹpẹ náà, wọn óo fi awọ ewúrẹ́ bò wọ́n, wọn óo sì ti ọ̀pá tí a fi ń gbé e bọ̀ ọ́. Nígbà tí ó bá tó àkókò láti tẹ̀síwájú, àwọn ìdílé Kohati yóo wá láti kó àwọn ohun èlò ibi mímọ́ lẹ́yìn tí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ bá ti bò wọ́n tán. Wọn kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan àwọn nǹkan mímọ́ náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kàn án yóo kú. “Eleasari ọmọ Aaroni Alufaa ni yóo ṣe ìtọ́jú òróró fìtílà, ati turari olóòórùn dídùn, ẹbọ ohun jíjẹ ati òróró ìyàsímímọ́, ati gbogbo Àgọ́ náà. Yóo máa ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́ ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ ati àwọn ohun èlò ibẹ̀.” OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé, “Ẹ má jẹ́ kí ìdílé Kohati parun láàrin ẹ̀yà Lefi, ohun tí ẹ óo ṣe sí wọn nìyí kí wọ́n má baà kú: nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ àwọn ohun mímọ́ jùlọ, Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ yóo wọ inú ibi mímọ́ lọ, wọn yóo sì sọ ohun tí olukuluku wọn yóo ṣe fún wọn, ati ẹrù tí olukuluku wọn yóo gbé. Àwọn ìdílé Kohati kò gbọdọ̀ wọ inú ibi mímọ́ láti yọjú wo àwọn ohun mímọ́, ẹnikẹ́ni tí ó bá yọjú wò wọ́n yóo kú.” OLUWA sọ fún Mose pé, “Ka iye àwọn ọmọ Geriṣoni ní ìdílé-ìdílé, gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn: ka àwọn ọkunrin wọn láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé aadọta, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ. Iṣẹ́ ìsìn ti àwọn ọmọ Geriṣoni nìyí: Àwọn ni yóo máa ru àwọn aṣọ ìkélé tí a fi ṣe ibi mímọ́, ati Àgọ́ Àjọ pẹlu àwọn ìbòrí rẹ̀, ati awọ ewúrẹ́ tí ń dán tí wọn fi bò ó, ati aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. Aṣọ ìkélé ti àgbàlá tí ó yí ibi mímọ́ ati pẹpẹ ká, aṣọ ìkélé fún ẹnu ọ̀nà àgbàlá, ati okùn wọn, ati gbogbo àwọn ohun tí wọn ń lò pẹlu wọn. Àwọn ni wọn óo máa ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ tí ó bá jẹ mọ́ àwọn nǹkan wọnyi. Kí Mose yan àwọn ọmọ Geriṣoni sí ìtọ́jú àwọn ẹrù, kí ó sì rí i pé wọ́n ṣe gbogbo ohun tí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ bá pa láṣẹ fún wọn nípa iṣẹ́ wọn. Iṣẹ́ àwọn ọmọ Geriṣoni ninu Àgọ́ Àjọ nìyí, Itamari ọmọ Aaroni alufaa ni yóo jẹ́ alabojuto wọn.” OLUWA sọ fún Mose pé, “Ka iye àwọn ọmọ Merari ní ìdílé-ìdílé, gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn. Kí o ka àwọn ọkunrin wọn láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé aadọta, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ. Àwọn ọmọ Merari ni yóo máa ru àwọn igi férémù Àgọ́, àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, àwọn òpó rẹ̀ ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Àwọn òpó àyíká àgbàlá ati ìtẹ́lẹ̀ wọn, àwọn èèkàn àgọ́, okùn wọn, ati gbogbo ohun tí wọn ń lò pẹlu wọn. Olukuluku yóo sì mọ ẹrù tirẹ̀. Iṣẹ́ àwọn ọmọ Merari ninu Àgọ́ Àjọ nìyí. Itamari ọmọ Aaroni alufaa ni yóo jẹ́ alabojuto wọn.” Mose, Aaroni ati àwọn olórí àwọn ọmọ Israẹli ka àwọn ọmọ Kohati ní ìdílé-ìdílé gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn. Láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé ẹni aadọta ọdún, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ. Iye wọ́n jẹ́ ẹgbẹrinla ó dín aadọta (2,750). Iye àwọn tí Mose ati Aaroni kà ninu àwọn ọmọ Kohati nìyí, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún wọn. Iye àwọn ọmọ Geriṣoni ní ìdílé-ìdílé, gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn, láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé aadọta, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ jẹ́ ẹgbẹtala ó lé ọgbọ̀n (2,630). Èyí ni iye àwọn tí Mose ati Aaroni kà ninu àwọn ọmọ Geriṣoni tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún wọn. Àwọn tí a kà ninu àwọn ọmọ Merari, ní ìdílé-ìdílé gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn, láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé aadọta ọdún, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ jẹ́ ẹgbẹrindinlogun (3,200). Èyí ni iye àwọn tí Mose ati Aaroni kà ninu àwọn ọmọ Merari gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún wọn. Gbogbo àwọn tí Mose, Aaroni ati àwọn olórí àwọn ọmọ Israẹli kà ninu àwọn ọmọ Lefi ní ìdílé-ìdílé gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn, láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé aadọta ọdún, gbogbo àwọn tí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ ìsìn ati iṣẹ́ ẹrù rírù ninu Àgọ́ Àjọ jẹ́ ẹgbaarin ó lé ẹgbẹta ó dín ogún (8,580). Mose ka àwọn eniyan náà, ó sì yan iṣẹ́ fún olukuluku wọn gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún un. OLUWA sọ fún Mose pé, “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọ́n lé gbogbo àwọn adẹ́tẹ̀ kúrò ní ibùdó wọn, gbogbo àwọn tí ó ni ọyún lára ati ẹnikẹ́ni tí ó di aláìmọ́ nípa fífi ọwọ́ kan òkú. Ẹ kó wọn sí ẹ̀yìn odi kí wọn má baà sọ ibùdó yín di aláìmọ́ nítorí pé mò ń gbé inú rẹ̀ pẹlu àwọn eniyan mi.” Àwọn ọmọ Israẹli sì yọ wọ́n kúrò láàrin wọn gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA. OLUWA sọ fún Mose pé: “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé nígbà tí ẹnikẹ́ni, bá dẹ́ṣẹ̀, tí ó bá rú òfin Ọlọ́run, tí olúwarẹ̀ sì jẹ̀bi, kí báà ṣe ọkunrin tabi obinrin, olúwarẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ó san ìtanràn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ó sì fi ìdámárùn-ún iye owó náà lé e fún ẹni tí ó ṣẹ̀. Ṣugbọn bí ẹni tí ó ṣẹ̀ náà bá ti kú, tí kò sì ní ìbátan tí ó lè gba owó ìtanràn náà, kí ó san owó náà fún àwọn alufaa OLUWA. Lẹ́yìn èyí ni yóo mú àgbò wá fún ẹbọ ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Àwọn alufaa ni wọ́n ni gbogbo àwọn ohun ìrúbọ, ati gbogbo ohun mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli bá mú wá sọ́dọ̀ wọn. Olukuluku alufaa yóo kó ohun tí wọ́n bá mú wá sọ́dọ̀ rẹ̀.” OLUWA sọ fún Mose pé kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Bí aya ẹnìkan bá ṣìṣe, tí ó hu ìwà àìtọ́ sí i; tí ọkunrin mìíràn bá bá a lòpọ̀, ṣugbọn tí ọkọ rẹ̀ kò ká wọn mọ́; ṣugbọn tí ó di ẹni ìbàjẹ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹlẹ́rìí nítorí pé ẹnìkankan kò rí wọn; tabi bí ẹnìkan bá ń jowú tí ó sì rò pé ọkunrin kan ń bá iyawo òun lòpọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀, kí olúwarẹ̀ mú iyawo rẹ̀ wá sọ́dọ̀ alufaa, kí ó sì mú ọrẹ rẹ̀ tíí ṣe ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa ìyẹ̀fun ọkà baali wá fún alufaa. Kò gbọdọ̀ da òróró sí orí rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì gbọdọ̀ fi turari sinu rẹ̀, nítorí pé ẹbọ owú ni, tí a rú láti múni ranti àìdára tí eniyan ṣe. “Alufaa yóo sì mú kí obinrin náà dúró níwájú pẹpẹ OLUWA, yóo da omi mímọ́ sinu àwo kan, yóo bù lára erùpẹ̀ ilẹ̀ Àgọ́ Àjọ sinu omi náà. Lẹ́yìn náà, alufaa yóo mú obinrin náà wá siwaju OLUWA, yóo tú irun orí obinrin náà, yóo sì gbé ẹbọ ìrántí lé e lọ́wọ́, tíí ṣe ẹbọ ohun jíjẹ ti owú. Àwo omi kíkorò, tí ó ń mú ègún wá yóo sì wà lọ́wọ́ alufaa. Nígbà náà ni alufaa yóo mú kí obinrin náà búra, yóo wí fún un pé, ‘Bí ọkunrin kankan kò bá bá ọ lòpọ̀, tí o kò sì ṣe aiṣootọ sí ọkọ rẹ, ègún inú omi kíkorò yìí kò ní ṣe ọ́ ní ibi. Ṣugbọn bí o bá tí ṣe alaiṣootọ sí ọkọ rẹ (níwọ̀n ìgbà tí o wà ní ilé rẹ̀), tí o sì ti sọ ara rẹ di aláìmọ́ nípa pé ọkunrin mìíràn bá ọ lòpọ̀, kí OLUWA sọ ọ́ di ẹni ègún ati ẹni ìfibú láàrin àwọn eniyan rẹ̀. Kí OLUWA mú kí abẹ́ rẹ rà, kí ó sì mú kí ara rẹ wú. Kí omi kíkorò tí ń mú ègún wá yìí wọ inú rẹ, kí ó mú kí inú rẹ wú, kí ó sì mú kí abẹ́ rẹ rà.’ “Obinrin náà yóo sì dáhùn pé, ‘Amin, Amin.’ “Lẹ́yìn èyí, kí alufaa kọ ègún yìí sinu ìwé, kí ó sì fọ̀ ọ́ sinu abọ́ omi kíkorò náà. Kí obinrin náà mu ún, omi náà yóo sì mú kí ó ní ìrora. Nígbà náà ni alufaa yóo gba ẹbọ ohun jíjẹ ti owú náà lọ́wọ́ obinrin náà yóo sì fì í níwájú OLUWA, lẹ́yìn èyí, yóo gbé e sórí pẹpẹ. Lẹ́yìn náà, alufaa yóo bu ẹ̀kúnwọ́ kan ninu ẹbọ ohun jíjẹ náà fún ẹbọ ìrántí, yóo sì sun ún lórí pẹpẹ; lẹ́yìn náà, yóo ní kí obinrin náà mu omi yìí. Bí ó bá jẹ́ pé obinrin náà ti ṣe alaiṣootọ sí ọkọ rẹ̀, tí ọkunrin mìíràn bá ti bá a lòpọ̀, omi náà yóo korò ninu rẹ̀, yóo sì mú kí inú rẹ̀ wú, kí abẹ́ rẹ̀ sì rà. Yóo sì fi bẹ́ẹ̀ di ẹni ègún láàrin àwọn eniyan rẹ̀. Ṣugbọn bí obinrin náà kò bá tí ì ba ara rẹ̀ jẹ́, ègún náà kò ní lágbára lórí rẹ̀, yóo sì lóyún. “Èyí ni ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe nígbà tí obinrin bá ṣe aiṣootọ sí ọkọ rẹ̀, tí ó sì ba ara rẹ̀ jẹ́ nítorí pé ọkunrin mìíràn bá a lòpọ̀; tabi nígbà tí ọkunrin kan bá ń ṣiyèméjì nípa ìdúró iyawo rẹ̀, ọkunrin náà yóo mú iyawo rẹ̀ wá siwaju OLÚWA, alufaa yóo sì ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ yìí. Nígbà náà ni ọkunrin náà yóo bọ́ ninu ẹ̀bi, ṣugbọn obinrin náà yóo forí ru ẹ̀bi àìdára tí ó ṣe.” OLUWA sọ fún Mose kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Nígbà tí ọkunrin tabi obinrin kan bá ṣe ìlérí láti di Nasiri, tí ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún OLUWA, yóo jáwọ́ kúrò ninu ọtí waini mímu, ati ọtí líle. Kò gbọdọ̀ mu ọtí kíkan tí a fi waini tabi ọtí líle ṣe. Kò gbọdọ̀ mu ọtí èso àjàrà, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ jẹ èso àjàrà tútù tabi gbígbẹ. Ní gbogbo ìgbà tí ó bá jẹ́ Nasiri, kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí a fi èso àjàrà ṣe, kì báà jẹ́ kóró tabi èèpo rẹ̀. “Kò gbọdọ̀ gé irun orí rẹ̀ tabi kí ó fá a títí tí ọjọ́ tí ó fi ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún OLUWA yóo fi pé, kí ó jẹ́ mímọ́, kí ó sì jẹ́ kí ìdì irun orí rẹ̀ máa dàgbà. Ní gbogbo ọjọ́ tí ó ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún OLUWA, kò gbọdọ̀ súnmọ́ òkú: kì báà ṣe òkú baba, tabi ti ìyá rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ súnmọ́ òkú arakunrin tabi arabinrin rẹ̀, nígbà tí wọ́n bá kú. Kò gbọdọ̀ ti ipasẹ̀ wọn sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nítorí ìyàsímímọ́ Ọlọrun ń bẹ lórí rẹ̀. Yóo jẹ́ mímọ́ fún OLUWA ní gbogbo ọjọ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀. “Bí ẹnìkan bá kú lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ lójijì, tí ó sì ti ipa bẹ́ẹ̀ sọ orí rẹ̀ di aláìmọ́; yóo dúró fún ọjọ́ meje. Ní ọjọ́ keje tí í ṣe ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, yóo fá irun orí rẹ̀. Ní ọjọ́ kẹjọ, yóo mú àdàbà meji tabi ọmọ ẹyẹlé meji tọ alufaa wá ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. Alufaa yóo fi ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, yóo fi ikeji rú ẹbọ sísun láti ṣe ètùtù fún un nítorí pé ó ti ṣẹ̀ nípa fífi ara kan òkú; yóo sì ya orí rẹ̀ sí mímọ́ ní ọjọ́ náà. Lẹ́yìn náà ni ọjọ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, a kì yóo ka àwọn ọjọ́ tí ó ti lò ṣáájú nítorí pé ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ ti bàjẹ́ nítorí pé ó fi ara kan òkú. Yóo sì mú ọ̀dọ́ àgbò, ọlọ́dún kan tọ alufaa wá fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi. “Èyí ni yóo jẹ́ òfin fún Nasiri: Nígbà tí ọjọ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ bá pé, yóo wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ pẹlu àwọn ọrẹ tí ó fẹ́ fún OLUWA: ọ̀dọ́ àgbò, ọlọ́dún kan, tí kò ní àbààwọ́n, fún ẹbọ sísun; abo ọ̀dọ́ aguntan, ọlọ́dún kan, tí kò ní àbààwọ́n, fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati àgbò kan tí kò ní àbààwọ́n fún ẹbọ alaafia, pẹlu burẹdi agbọ̀n kan, tí kò ní ìwúkàrà ninu, ati burẹdi aládùn tí a fi ìyẹ̀fun dáradára, tí a fi òróró pò ṣe, ati burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí kò ní ìwúkàrà ninu, tí a ta òróró sí lórí, ati ẹbọ ohun jíjẹ, ati ti ohun mímu. “Alufaa yóo sì kó àwọn nǹkan wọnyi wá siwaju OLUWA, yóo rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹbọ sísun rẹ̀. Yóo fi àgbò náà rú ẹbọ alaafia sí OLUWA pẹlu burẹdi agbọ̀n kan tí kò ní ìwúkàrà ninu. Alufaa yóo fi ohun jíjẹ ati ohun mímu rẹ̀ rúbọ pẹlu. Nasiri náà yóo fá irun orí rẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, yóo sì fi irun náà sinu iná tí ó wà lábẹ́ ẹbọ alaafia. Alufaa yóo fún Nasiri náà ní apá àgbò tí a ti bọ̀ pẹlu burẹdi dídùn kan tí kò ní ìwúkàrà ninu, ati burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kan tí kò ní ìwúkàrà ninu, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti fá irun orí rẹ̀. Lẹ́yìn náà ni alufaa yóo fi àwọn ẹbọ náà níwájú OLUWA. Mímọ́ ni wọ́n jẹ́ fún alufaa náà, pẹlu àyà tí a fì ati itan tí wọ́n fi rúbọ. Lẹ́yìn èyí, Nasiri náà lè máa mu ọtí waini. “Èyí ni òfin Nasiri, ṣugbọn bí Nasiri kan bá ṣe ìlérí ju ẹbọ tí òfin là sílẹ̀ lọ, ó gbọdọ̀ mú ìlérí náà ṣẹ.” OLUWA sọ fún Mose pé kí ó sọ fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Báyìí ni ẹ óo máa súre fún àwọn ọmọ Israẹli. ‘Kí OLUWA bukun yín, kí ó sì pa yín mọ́. Kí OLUWA mú kí ojú rẹ̀ mọ́lẹ̀ sí yín lára, kí ó sì ṣàánú fún yín. Kí OLUWA bojúwò yín, kí ó sì fún yín ní alaafia.’ “Bẹ́ẹ̀ ni wọn óo fi orúkọ mi súre fún àwọn ọmọ Israẹli, n óo sì bukun wọn.” Ní ọjọ́ tí Mose gbé Àgọ́ Àjọ dúró, tí ó sì ta òróró sí i tòun ti gbogbo nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀, ati pẹpẹ pẹlu gbogbo ohun èlò rẹ̀, àwọn olórí àwọn ẹ̀yà Israẹli, tí wọ́n jẹ́ olórí ní ìdílé wọn, tí wọ́n sì wà pẹlu Mose nígbà tí ó ka àwọn eniyan Israẹli, mú ọrẹ ẹbọ wá siwaju OLUWA. Ọkọ̀ ẹrù mẹfa ati akọ mààlúù mejila. Ọkọ̀ ẹrù kọ̀ọ̀kan fún olórí meji meji, ati akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan fún olórí kọ̀ọ̀kan. Wọ́n mú àwọn ẹbọ wọnyi wá sí ẹnu ọ̀nà ibi mímọ́. OLUWA sọ fún Mose pé kí ó gba àwọn ẹbọ náà lọ́wọ́ wọn fún lílò ninu Àgọ́ Àjọ, kí ó sì pín wọn fún olukuluku àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìsìn olukuluku wọn ti rí. Mose bá gba àwọn ọkọ̀ ẹrù ati àwọn akọ mààlúù náà, ó kó wọn fún àwọn ọmọ Lefi. Ó fún àwọn ọmọ Geriṣoni ní ọkọ̀ ẹrù meji ati akọ mààlúù mẹrin, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìsìn wọn. Ó fún àwọn ọmọ Merari ní ọkọ̀ ẹrù mẹrin ati akọ mààlúù mẹjọ, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìsìn wọn, lábẹ́ àkóso Itamari ọmọ Aaroni alufaa. Ṣugbọn àwọn ọmọ Kohati ni Mose kò fún ní nǹkankan, nítorí pé àwọn ohun mímọ́ tí wọ́n máa ń fi èjìká rù ni iṣẹ́ ìsìn wọn jẹ mọ́. Àwọn olórí náà rú ẹbọ fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ ní ọjọ́ tí wọ́n ta òróró sí i, láti yà á sí mímọ́. Wọ́n mú ẹbọ wọn wá siwaju pẹpẹ. OLUWA sọ fún Mose pé, “Kí olukuluku olórí mú ọrẹ ẹbọ tirẹ̀ fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ wá ní ọjọ́ tirẹ̀.” Ní ọjọ́ kinni, Naṣoni ọmọ Aminadabu, olórí ẹ̀yà Juda mú ẹbọ tirẹ̀ wá. Ọrẹ ẹbọ rẹ̀ ni: àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli, ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, fún ẹbọ ohun jíjẹ. Àwo kòtò tí wọ́n fi wúrà ṣe kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari; akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò kan, ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun; ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ó kó àwọn nǹkan wọnyi kalẹ̀ fún ẹbọ alaafia: akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan. Wọ́n jẹ́ ọrẹ ẹbọ Naṣoni, ọmọ Aminadabu. Ní ọjọ́ keji ni Netaneli ọmọ Suari olórí ẹ̀yà Isakari mú ọrẹ tirẹ̀ wá. Ọrẹ ẹbọ tirẹ̀ ni: àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ jẹ́ aadọrin ṣekeli, ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, fún ẹbọ ohun jíjẹ; ṣíbí wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari; akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan ati ọ̀dọ́ àgbò kan, ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun; òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ó sì mú akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan wá fún ẹbọ alaafia. Wọ́n jẹ́ ọrẹ Netaneli ọmọ Suari. Ní ọjọ́ kẹta Eliabu ọmọ Heloni, olórí ẹ̀yà Sebuluni mú ọrẹ tirẹ̀ wá. Ọrẹ tirẹ̀ ni: àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní Àgọ́ Àjọ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ. Ṣíbí wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá tí ó sì kún fún turari. Akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan ati ọ̀dọ́ àgbò ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun. Òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ó sì mú akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un, ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan wá fún ẹbọ alaafia. Èyí ni ọrẹ Eliabu ọmọ Heloni. Ní ọjọ́ kẹrin Elisuri ọmọ Ṣedeuri, olórí ẹ̀yà Reubẹni mú ọrẹ tirẹ̀ wá. Ọrẹ tirẹ̀ ni: àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli, ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ, ṣíbí wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá tí ó sì kún fún turari. Akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan, ati ọ̀dọ́ àgbò ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun, ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ó sì mú akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un ati akọ ọ̀dọ́ aguntan marun-un ọlọ́dún kan wá fún ẹbọ alaafia. Ọrẹ ti Elisuri ọmọ Ṣedeuri nìyí. Ní ọjọ́ karun-un, Ṣelumieli ọmọ Suriṣadai, olórí ẹ̀yà Simeoni mú ọrẹ tirẹ̀ wa. Ọrẹ rẹ̀ ni àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ. Ara ọrẹ rẹ̀ tún ni: àwo kòtò kan tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari, akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun, ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Lẹ́yìn náà, Ṣelumieli, ọmọ Suriṣadai tún ko akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un, ati akọ ọ̀dọ́ aguntan marun-un ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan kalẹ̀ fún ẹbọ alaafia. Ní ọjọ́ kẹfa ni Eliasafu, ọmọ Deueli, olórí àwọn ẹ̀yà Gadi, mú ọrẹ tirẹ̀ wá. Ọrẹ tirẹ̀ ni: àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin (70) ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, fún ẹbọ ohun jíjẹ. Ara ọrẹ rẹ̀ tún ni: àwo kòtò kan tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari, akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò kan ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun; ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Lẹ́yìn náà Eliasafu, ọmọ Deueli, tún ko akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un, ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan kalẹ̀ fún ẹbọ alaafia. Ní ọjọ́ keje ni Eliṣama ọmọ Amihudu, olórí àwọn ẹ̀yà Efuraimu mú ọrẹ tirẹ̀ wá. Ọrẹ tirẹ̀ ni àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli ati abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ. Ara ọrẹ rẹ̀ tún ni àwo kòtò kan tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari. Akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò kan ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun, ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Eliṣama, ọmọ Amihudu, kó akọ mààlúù meji, ati àgbò marun-un, òbúkọ marun-un ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un, ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan sílẹ̀ fún ẹbọ alaafia. Ní ọjọ́ kẹjọ ni Gamalieli ọmọ Pedasuri, olórí àwọn ẹ̀yà Manase mú ọrẹ ẹbọ tirẹ̀ wá. Ọrẹ tirẹ̀ ni: àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, fún ẹbọ ohun jíjẹ. Ara ọrẹ rẹ̀ tún ni àwo kòtò kan tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari, akọ mààlúù kékeré kan, ati àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò kan, ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun, ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Gamalieli ọmọ Pedasuri, kó àwọn akọ mààlúù meji ati àgbò marun-un, òbúkọ marun-un ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un, ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan sílẹ̀ fún ẹbọ alaafia. Ní ọjọ́ kẹsan-an ni Abidani ọmọ Gideoni, olórí àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini mú ọrẹ tirẹ̀ wá. Ọrẹ tirẹ̀ ni àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọ́n ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, fún ẹbọ ohun jíjẹ. Ara ọrẹ rẹ̀ tún ni: àwo kòtò kan, tí wọ́n fi wúrà ṣe tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari. Akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò, ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun, ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Abidani ọmọ Gideoni, kó akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un, ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un, ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan sílẹ̀ fún ẹbọ alaafia. Ní ọjọ́ kẹwaa ni Ahieseri ọmọ Amiṣadai, olórí àwọn ẹ̀yà Dani mú ọrẹ tirẹ̀ wá. Ọrẹ tirẹ̀ ni àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ. Ara àwọn ọrẹ rẹ̀ tún ni: àwo kòtò kan tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari. Akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò kan, ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun, ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ahieseri ọmọ Amiṣadai, kó akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un ati akọ ọ̀dọ́ aguntan marun-un, ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan wá fún ẹbọ alaafia. Ní ọjọ́ kọkanla ni Pagieli ọmọ Okirani, olórí àwọn ẹ̀yà Aṣeri mú ọrẹ tirẹ̀ wá. Ọrẹ tirẹ̀ ni: àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ẹbọ ohun jíjẹ. Ara àwọn ọrẹ rẹ̀ tún ni àwo kòtò kan tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá tí ó sì kún fún turari; akọ mààlúù kékeré kan ati àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò kan ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun, ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Pagieli ọmọ Okirani, kó akọ mààlúù meji ati àgbò marun-un kalẹ̀, pẹlu òbúkọ marun-un, ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un, ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, fún ẹbọ alaafia. Ní ọjọ́ kejila ni Ahira ọmọ Enani, olórí àwọn ẹ̀yà Nafutali, mú ọrẹ tirẹ̀ wá. Ọrẹ tirẹ̀ ni: àwo fadaka kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, pẹlu abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ẹbọ ohun jíjẹ. Ara àwọn ọrẹ rẹ̀ tún ni: àwo kòtò kan, tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari; akọ mààlúù kékeré kan ati àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò kan ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun; ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ahira, ọmọ Enani, kó akọ mààlúù meji ati àgbò marun-un, òbúkọ marun-un, ọ̀dọ́ àgbò marun-un, ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan wá fún ẹbọ alaafia. Ní àpapọ̀, àwọn nǹkan ọrẹ tí àwọn olórí mú wá fún yíya pẹpẹ sí mímọ́ ní ọjọ́ tí a fi àmì òróró yà á sí mímọ́ ni: abọ́ fadaka mejila, àwo fadaka mejila, àwo kòtò tí wọ́n fi wúrà ṣe mejila, ìwọ̀n àwo fadaka kọ̀ọ̀kan jẹ́ aadoje (130) ṣekeli; ìwọ̀n gbogbo àwọn abọ́ fadaka náà jẹ́ ẹgbaa ṣekeli ó lé irinwo (2,400). Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n wọ́n. Ìwọ̀n ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn àwo kòtò mejeejila tí wọ́n kún fún turari jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá mẹ́wàá. Ìwọ̀n ṣekeli tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n wọ́n. Ìwọ̀n àwọn àwo kòtò tí wọ́n fi wúrà ṣe jẹ́ ọgọfa (120) ṣekeli. Gbogbo mààlúù tí wọ́n mú wá fún ọrẹ ẹbọ sísun jẹ́ mejila ati àgbò mejila, ọ̀dọ́ àgbò mejila ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ. Wọ́n tún mú òbúkọ mejila wá fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Àwọn nǹkan tí wọ́n kó kalẹ̀ fún ẹbọ alaafia ni: akọ mààlúù mẹrinlelogun pẹlu ọgọta àgbò; ọgọta òbúkọ, ọgọta ọ̀dọ́ àgbò ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan. Wọ́n kó gbogbo wọn wá fún ọrẹ ẹbọ fún yíya pẹpẹ sí mímọ́, lẹ́yìn tí wọ́n ta òróró sí i. Nígbà tí Mose wọ inú àgọ́ ìpàdé lọ láti bá OLUWA sọ̀rọ̀, ó gbọ́ ohùn kan tí ń bá a sọ̀rọ̀ láti orí ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí àpótí ẹ̀rí, láàrin àwọn kerubu mejeeji. Ẹni náà bá Mose sọ̀rọ̀. OLUWA rán Mose pé kí ó sọ fún Aaroni pé, nígbà tí Aaroni bá tan fìtílà mejeeje, kí ó gbé wọn sórí ọ̀pá fìtílà kí wọ́n lè tan ìmọ́lẹ̀ siwaju ọ̀pá náà. Aaroni gbé àwọn fìtílà náà ka orí ọ̀pá wọn, kí wọ́n lè tan ìmọ́lẹ̀ siwaju, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. Wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni wọ́n fi ṣe ọ̀pá fìtílà náà, láti ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ títí dé ìtànná orí rẹ̀. Mose ṣe ọ̀pá fìtílà náà gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí OLUWA fi hàn án. OLUWA sọ fún Mose pé, “Ya àwọn ọmọ Lefi sọ́tọ̀ láàrin àwọn ọmọ Israẹli, kí o sì wẹ̀ wọ́n mọ́. Kí o wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ sí wọn lára, kí wọ́n fi abẹ fá gbogbo irun ara wọn, kí wọ́n sì fọ aṣọ wọn, kí wọ́n sì di mímọ́. Kí wọ́n mú akọ mààlúù kékeré kan ati ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ wá. Kí wọ́n sì mú akọ mààlúù kékeré mìíràn wá, fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Lẹ́yìn náà, pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, kí àwọn ọmọ Lefi sì dúró ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. Kó àwọn ọmọ Lefi wá siwaju OLUWA, kí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì gbé ọwọ́ lé wọn lórí, kí Aaroni alufaa wá ya àwọn ọmọ Lefi sọ́tọ̀ bí ọrẹ fífì láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli, kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ ìsìn OLÚWA. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Lefi yóo gbé ọwọ́ wọn lé àwọn akọ mààlúù náà lórí. O óo fi ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, o óo sì fi ikeji rú ẹbọ sísun sí OLÚWA, láti ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Lefi. “Ya àwọn ọmọ Lefi sọ́tọ̀ fún mi gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli; wọn óo sì máa ṣe iranṣẹ fún Aaroni alufaa ati àwọn ọmọ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni o óo ṣe ya àwọn ọmọ Lefi sọ́tọ̀ láàrin àwọn ọmọ Israẹli, wọn óo sì jẹ́ tèmi. Lẹ́yìn tí o bá ti wẹ̀ wọ́n mọ́, tí o sì ti yà wọ́n sọ́tọ̀ bí ẹbọ fífì sí OLUWA, ni àwọn ọmọ Lefi tó lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ. Mo ti gbà wọ́n dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì di tèmi patapata. Nígbà tí mo pa gbogbo àkọ́bí ní Ijipti ni mo ti ya gbogbo àkọ́bí ninu àwọn ọmọ Israẹli sọ́tọ̀ láti jẹ́ tèmi. Ṣugbọn nisinsinyii, mo ti gba àwọn ọmọ Lefi dípò gbogbo àkọ́bí ninu àwọn ọmọ Israẹli. Mo ti fi àwọn ọmọ Lefi fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ láti inú àwọn ọmọ Israẹli, láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn ninu Àgọ́ Àjọ ati láti máa ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli, kí àjàkálẹ̀ àrùn má baà bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn nígbà tí wọn bá súnmọ́ ibi mímọ́.” Mose ati Aaroni ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì ya àwọn ọmọ Lefi sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose pé kí wọ́n ṣe. Àwọn ọmọ Lefi wẹ ara wọn mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n sì fọ aṣọ wọn. Aaroni yà wọ́n sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì fún OLUWA, ó sì ṣe ètùtù fún wọn láti wẹ̀ wọ́n mọ́. Lẹ́yìn náà àwọn ọmọ Lefi bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ, wọ́n ń ṣe iranṣẹ fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀. Bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose pé kí àwọn ọmọ Israẹli ṣe fun àwọn ọmọ Lefi, ni wọ́n ṣe. OLUWA sọ fún Mose pé, “Àwọn ọmọ Lefi yóo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn wọn ninu Àgọ́ Àjọ láti ìgbà tí wọ́n bá ti di ẹni ọdún mẹẹdọgbọn. Nígbà tí wọ́n bá di ẹni aadọta ọdún, iṣẹ́ wọn ninu Àgọ́ Àjọ yóo dópin. Wọn kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ níbẹ̀ mọ́, ṣugbọn wọ́n lè máa ran àwọn arakunrin wọn lọ́wọ́ nípa bíbojú tó wọn; ṣugbọn àwọn gan-an kò gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ níbẹ̀ mọ́. Bẹ́ẹ̀ ni kí o ṣe yan iṣẹ́ ìsìn àwọn ọmọ Lefi fún wọn.” Ní oṣù kinni, ọdún keji tí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní Ijipti, OLUWA sọ fún Mose ninu aṣálẹ̀ Sinai pé, “Kí àwọn ọmọ Israẹli máa ṣe Àjọ̀dún ìrékọjá ní àkókò rẹ̀. Ní ọjọ́ kẹrinla oṣù yìí, láti àṣáálẹ́ ni àwọn ọmọ Israẹli yóo ti máa ṣe Àjọ̀dún ìrékọjá gẹ́gẹ́ bí òfin ati ìlànà rẹ̀.” Mose bá sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọ́n ṣe Àjọ̀dún ìrékọjá. Wọn sì ṣe é ní àṣáálẹ́ ọjọ́ kẹrinla oṣù kinni ní aṣálẹ̀ Sinai. Àwọn eniyan náà ṣe gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fun wọn. Ṣugbọn àwọn kan wà tí wọn kò lè bá wọn ṣe ọdún náà nítorí pé wọ́n jẹ́ aláìmọ́ nípa fífi ọwọ́ kan òkú. Wọ́n wá sọ́dọ̀ Mose ati Aaroni, wọ́n sì sọ fún wọn pé, “Nítòótọ́, a ti di aláìmọ́ nítorí pé a fi ọwọ́ kan òkú, ṣugbọn kí ló dé tí a kò fi lè mú ọrẹ ẹbọ wa wá fún OLUWA gẹ́gẹ́ bí àwọn arakunrin wa?” Mose bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ dúró di ìgbà tí mo bá gbọ́ àṣẹ tí OLUWA yóo pa nípa yín.” OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, nígbà tí ọ̀kan ninu yín tabi àwọn ọmọ yín bá di aláìmọ́ nítorí pé ó fi ọwọ́ kan òkú; tabi ó wà ní ìrìn àjò, ṣugbọn tí ọkàn rẹ̀ sì fẹ́ ṣe Àjọ̀dún ìrékọjá. Anfaani wà fun yín pé kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣe é ní ọjọ́ kẹrinla oṣù keji. Kí ó ṣe é pẹlu burẹdi tí a kò fi ìwúkàrà sí ati ewébẹ̀ kíkorò. Ẹ kò gbọdọ̀ fi àjẹkù kankan sílẹ̀ di ọjọ́ keji, ẹ kò sì gbọdọ̀ fọ́ ọ̀kankan ninu egungun ẹran tí ẹ bá fi rú ẹbọ náà. Ẹ óo ṣe ọdún Àjọ̀dún Ìrékọjá náà gẹ́gẹ́ bí òfin ati ìlànà rẹ̀. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ́, tí kò lọ sí ìrìn àjò, ṣugbọn tí kò ṣe Àjọ̀dún Ìrékọjá ni a ó yọ kúrò láàrin àwọn eniyan mi, nítorí kò mú ọrẹ ẹbọ wá fún OLUWA ní àkókò rẹ̀. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ níláti jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. “Bí àlejò kan bá wà ní ààrin yín tí ó sì fẹ́ ṣe Àjọ̀dún Ìrékọjá, yóo ṣe é gẹ́gẹ́ bí òfin ati ìlànà rẹ̀. Òfin ati ìlànà kan náà ni ó wà fún gbogbo yín, ati onílé ati àlejò.” Ní ọjọ́ tí wọn pa Àgọ́ Àjọ, èyí tí í ṣe Àgọ́ Ẹ̀rí, ìkùukùu bò ó. Ní alẹ́, ìkùukùu náà dàbí ọ̀wọ̀n iná. Ìkùukùu ni lọ́sàn-án, ṣugbọn ní alẹ́, ó dàbí ọ̀wọ̀n iná. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì máa ń rí nígbà gbogbo. Nígbà tí ìkùukùu yìí bá kúrò ní orí Àgọ́ Àjọ àwọn ọmọ Israẹli yóo tú àgọ́ wọn palẹ̀, wọn yóo sì lọ tún un pa níbi tí ìkùukùu náà bá ti dúró. Àṣẹ OLUWA ni àwọn ọmọ Israẹli ń tẹ̀lé láti tú àgọ́ wọn palẹ̀ ati láti tún àgọ́ wọn pa. Níwọ̀n ìgbà tí ìkùukùu náà bá ti wà ní orí Àgọ́ Àjọ, àwọn ọmọ Israẹli yóo dúró ninu àgọ́ wọn. Nígbà tí ìkùukùu náà tilẹ̀ dúró pẹ́ ní orí Àgọ́, àwọn ọmọ Israẹli ṣe ìgbọràn sí OLUWA, wọ́n dúró ninu àgọ́ wọn. Ìgbà mìíràn ẹ̀wẹ̀, ìkùukùu náà yóo dúró lórí Àgọ́ Àjọ fún ọjọ́ bíi mélòó péré. Sibẹsibẹ, àṣẹ OLUWA ni àwọn ọmọ Israẹli ń tẹ̀lé kì báà ṣe pé ó jẹ mọ́ pé kí wọn tú àgọ́ wọn palẹ̀ ni tabi pé kí wọ́n tún un pa. Nígbà mìíràn, ìkùukùu náà lè má dúró lórí Àgọ́ Àjọ ju àṣáálẹ́ títí di òwúrọ̀ lọ, sibẹsibẹ, nígbàkúùgbà tí ìkùukùu bá kúrò lórí Àgọ́ Àjọ ni àwọn ọmọ Israẹli máa ń tẹ̀síwájú. Kì báà sì jẹ́ ọjọ́ meji ni, tabi oṣù kan, tabi ọdún kan tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, níwọ̀n ìgbà tí ìkùukùu náà bá sì wà ní orí Àgọ́ Àjọ, wọn yóo dúró ni. Ṣugbọn bí ó bá ti gbéra ni àwọn náà yóo tẹ̀síwájú. Nígbà tí OLUWA bá fún wọn láṣẹ ni wọ́n máa ń pàgọ́, nígbà tí ó bá sì tó fún wọn láṣẹ ni wọ́n tó máa ń gbéra. OLUWA sọ fún Mose pé, “Fi fadaka tí wọ́n fi òòlù lù ṣe fèrè meji fún pípe àwọn ọmọ Israẹli jọ ati títú ibùdó palẹ̀. Nígbà tí àwọn afọnfèrè bá fọn fèrè mejeeji, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli yóo wá sọ́dọ̀ rẹ ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé fèrè kan ni wọ́n fọn, àwọn olórí ẹ̀yà Israẹli nìkan ni yóo wá sọ́dọ̀ rẹ. Nígbà tí ẹ bá kọ́ fọn fèrè ìdágìrì, àwọn tí wọ́n pa àgọ́ sí ìhà ìlà oòrùn Àgọ́ yóo ṣí, wọn yóo sì tẹ̀síwájú. Bí ẹ bá fọn fèrè ìdágìrì lẹẹkeji, àwọn tí wọ́n pàgọ́ sí ìhà gúsù yóo ṣí, wọn yóo sì tẹ̀síwájú. Ìgbàkúùgbà tí ẹ bá fẹ́ tẹ̀síwájú ni kí ẹ máa fọn fèrè ìdágìrì. Nígbà tí ẹ bá fẹ́ pe àwọn ọmọ Israẹli jọ ẹ óo máa fọn fèrè, ṣugbọn kò ní jẹ́ ti ìdágìrì. Àwọn alufaa, ọmọ Aaroni ni yóo máa fọn fèrè náà. “Fèrè yìí yóo sì jẹ́ ìlànà fún ìrandíran yín. Nígbà tí ẹ bá ń lọ bá àwọn ọ̀tá yín jà lójú ogun láti gba ara yín lọ́wọ́ àwọn tí ń ni yín lára, ẹ óo fọn fèrè ìdágìrì. OLUWA Ọlọrun yín yóo sì ranti yín, yóo sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín. Ẹ óo máa fọn àwọn fèrè náà ní ọjọ́ ayọ̀, ní àwọn ọjọ́ àjọ̀dún yín ati ní ọjọ́ kinni oṣù. Ẹ óo máa fọn wọ́n nígbà tí ẹ bá mú ọrẹ ẹbọ sísun ati ọrẹ ẹbọ alaafia yín wá fún Ọlọrun. Yóo jẹ́ àmì ìrántí fun yín níwájú Ọlọrun yín. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.” Ní ogúnjọ́ oṣù keji, ní ọdún keji tí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní Ijipti, ìkùukùu tí ó wà ní orí ibi mímọ́ gbéra sókè. Àwọn ọmọ Israẹli sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn láti aṣálẹ̀ Sinai, wọ́n tò lẹ́sẹẹsẹ. Ìkùukùu náà bá dúró ní aṣálẹ̀ Parani. Ìgbà kinni nìyí tí wọn yóo tẹ̀síwájú gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa láti ẹnu Mose. Àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ ọ̀págun ẹ̀yà Juda ni wọ́n kọ́kọ́ ṣí, wọ́n tò ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Naṣoni ọmọ Aminadabu ni olórí wọn. Netaneli ọmọ Suari ni olórí ẹ̀yà Isakari. Olórí ẹ̀yà Sebuluni sì ni Eliabu ọmọ Heloni. Nígbà tí wọ́n tú Àgọ́ Àjọ palẹ̀, àwọn ọmọ Geriṣoni ati àwọn ọmọ Merari tí ó ru Àgọ́ Àjọ náà ṣí tẹ̀lé àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ ọ̀págun Juda. Lẹ́yìn náà ni àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ ọ̀págun ẹ̀yà Reubẹni ṣí, wọ́n tò ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Elisuri ọmọ Ṣedeuri ni olórí wọn. Ṣelumieli ọmọ Suriṣadai ni olórí ẹ̀yà Simeoni. Olórí ẹ̀yà Gadi sì ni Eliasafu ọmọ Deueli. Lẹ́yìn wọn ni àwọn ọmọ Kohati tí wọ́n ru àwọn ohun èlò mímọ́ tó ṣí. Èyí jẹ́ kí àwọn ọmọ Geriṣoni ati àwọn ọmọ Merari rí ààyè láti pa Àgọ́ Àjọ náà kí àwọn ọmọ Kohati tó dé. Lẹ́yìn náà ni àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ ọ̀págun ẹ̀yà Efuraimu ṣí, wọ́n tò ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Eliṣama ọmọ Amihudu ni olórí wọn. Gamalieli ọmọ Pedasuri ni olórí ẹ̀yà Manase. Olórí ẹ̀yà Bẹnjamini sì ni Abidani ọmọ Gideoni. Ní ìparí, àwọn ẹ̀yà tí wọ́n wà lábẹ́ ọ̀págun Dani ṣí, wọ́n tò ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Ahieseri ọmọ Amiṣadai ni olórí wọn. Pagieli ọmọ Okirani ni olórí ẹ̀yà Aṣeri. Olórí ẹ̀yà Nafutali sì ni Ahira ọmọ Enani. Bẹ́ẹ̀ ni ètò ìrìn àjò àwọn ọmọ Israẹli rí nígbà tí wọ́n ṣí kúrò ní ibùdó wọn. Mose sọ fún Hobabu ọmọ Reueli, baba iyawo rẹ̀, ará Midiani, pé: “Àwa ń lọ sí ilẹ̀ tí OLUWA ti ṣe ìlérí láti fún wa, máa bá wa kálọ, a óo sì ṣe ọ́ dáradára, nítorí OLUWA ti ṣe ìlérí ibukun fún Israẹli.” Ṣugbọn Hobabu dá a lóhùn pé: “Rárá o, n óo pada sí ilẹ̀ mi ati sọ́dọ̀ àwọn eniyan mi.” Mose sì wí pé: “Jọ̀wọ́ má fi wá sílẹ̀, nítorí pé o mọ aṣálẹ̀ yìí dáradára, o sì lè máa darí wa sí ibi tí ó yẹ kí á pa àgọ́ wa sí. Bí o bá bá wa lọ, OLUWA yóo fún ìwọ náà ninu ibukun tí ó bá fún wa.” Wọ́n bá gbéra kúrò ní Sinai, òkè OLUWA, wọ́n rìn fún ọjọ́ mẹta. Àpótí Majẹmu OLUWA sì wà níwájú wọn láti bá wọn wá ibi ìsinmi tí wọn yóo pàgọ́ sí. Bí wọ́n ti ń ṣí ní ibùdó kọ̀ọ̀kan, ìkùukùu OLUWA ń wà lórí wọn ní ọ̀sán. Nígbàkúùgbà tí Àpótí Majẹmu OLUWA bá ṣí, Mose á wí pé, “Dìde, OLUWA, kí o sì tú àwọn ọ̀tá rẹ ká, kí o sì mú kí àwọn tí ó kórìíra rẹ sá.” Nígbàkúùgbà tí ó bá sì dúró, yóo wí pé “OLUWA, pada sọ́dọ̀ ẹgbẹẹgbẹrun àwọn eniyan Israẹli.” Nígbà tí ó yá àwọn eniyan náà bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí OLUWA nípa ìṣòro wọn. Nígbà tí OLUWA gbọ́ kíkùn wọn, inú bí i, ó sì fi iná jó wọn; iná náà run gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní òpin ibùdó náà. Àwọn eniyan náà sì ké tọ Mose wá fún ìrànlọ́wọ́. Mose gbadura fún wọn, iná náà sì kú. Wọ́n pe orúkọ ibẹ̀ ní Tabera, nítorí níbẹ̀ ni iná OLUWA ti jó láàrin wọn. Àwọn àjèjì tí wọ́n wà láàrin àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí kùn, pé àwọn kò rí ẹran jẹ bí ìgbà tí àwọn wà ní Ijipti. Àwọn ọmọ Israẹli pàápàá bẹ̀rẹ̀ sí sọkún àìrẹ́ran jẹ. Wọ́n ń sọ pé, “Ó mà ṣe o, a kò rí ẹran jẹ! Ní Ijipti, à ń jẹ ẹja ati apálà, ẹ̀gúsí, ewébẹ̀, alubọsa ati galiki. Ṣugbọn nisinsinyii, a kò lókun ninu mọ́, kò sí ohun tí a rí jẹ bíkòṣe mana yìí nìkan lojoojumọ.” Mana náà sì dàbí èso korianda, tí àwọ̀ rẹ̀ dàbí kóró òkúta bideliumi. Àwọn eniyan náà a máa lọ kó wọn láàárọ̀, wọn á lọ̀ ọ́ tabi kí wọn gún un lódó láti fi ṣe ìyẹ̀fun. Wọn á sè é ninu ìkòkò, wọn á fi ṣe bíi àkàrà, adùn rẹ̀ sì dàbí ti àkàrà dídùn tí a fi òróró olifi dín. Òròòru ni mana náà máa ń bọ́ nígbà tí ìrì bá ń sẹ̀ ní ibùdó. Mose gbọ́ bí àwọn eniyan náà ti ń sọkún lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ wọn, olukuluku pẹlu àwọn ará ilé rẹ̀. Ọ̀rọ̀ náà dun Mose, ibinu OLUWA sì ru sí àwọn eniyan náà. Mose bá wí fún OLUWA pé, “Kí ló dé tí o ṣe mí báyìí? Kí ló dé tí n kò rí ojurere rẹ, tí o sì di ẹrù gbogbo àwọn eniyan wọnyi rù mí? Ṣé èmi ni mo lóyún wọn ni, àbí èmi ni mo bí wọn, tí o fi sọ fún mi pé kí n gbé wọn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ọmú lọ sí ilẹ̀ tí o ti ṣe ìlérí fún àwọn baba wọn. Níbo ni kí n ti rí ẹran tí yóo tó fún àwọn eniyan wọnyi? Wò ó! Wọ́n ń sọkún níwájú mi; wọ́n ń wí pé kí n fún àwọn ní ẹran jẹ. Èmi nìkan kò lè ṣe àkóso àwọn eniyan wọnyi; ẹrù náà wúwo jù fún mi. Bí ó bá jẹ́ pé bí o óo ti ṣe mí nìyí, mo bẹ̀ ọ́, kúkú pa mí bí inú rẹ bá yọ́ sí mi, kí n má baà kan àbùkù.” OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Yan aadọrin ninu àwọn àgbààgbà Israẹli, àwọn tí àwọn ọmọ Israẹli mọ̀ ní olórí, kí o sì mú wọn wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. Kí wọ́n dúró pẹlu rẹ níbẹ̀. N óo wá bá ọ sọ̀rọ̀ níbẹ̀. N óo mú lára ẹ̀mí tí ó wà lára rẹ, n óo fi sí wọn lára; kí wọn lè máa ràn ọ́ lọ́wọ́, láti gbé ẹrù àwọn eniyan náà, kí ìwọ nìkan má baà máa ṣe iṣẹ́ náà. Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí ẹ ya ara yín sí mímọ́, ẹ óo jẹ ẹran lọ́la. OLUWA ti gbọ́ ẹkún ati ìráhùn yín pé, ‘Ta ni yóo fún wa ní ẹran jẹ, ó sàn fún wa jù báyìí lọ ní ilẹ̀ Ijipti.’ Nítorí náà OLUWA yóo fun yín ní ẹran. Kì í ṣe èyí tí ẹ óo jẹ ní ọjọ́ kan, tabi ọjọ́ meji, tabi ọjọ́ marun-un, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe fún ọjọ́ mẹ́wàá, tabi fún ogúnjọ́. Ṣugbọn odidi oṣù kan ni ẹ óo fi jẹ ẹ́, títí tí yóo fi fẹ́rẹ̀ hù lórí yín, tí yóo sì sú yín, nítorí pé ẹ ti kọ OLUWA tí ó wà láàrin yín sílẹ̀, ẹ sì ti ráhùn níwájú rẹ̀ pé: ‘Kí ló dé tí a fi kúrò ní Ijipti.’ ” Mose sì sọ fún OLUWA pé, “Àwọn tí wọn tó ogun jà nìkan ninu àwọn eniyan tí mò ń ṣe àkóso wọn yìí jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ (600,000) o sì wí pé o óo fún wọn ní ẹran jẹ fún oṣù kan. Ṣé a lè rí mààlúù tabi aguntan tí yóo tó láti pa fún wọn? Ǹjẹ́ gbogbo ẹja tí ó wà ninu òkun tó fún wọn bí?” OLUWA dá Mose lóhùn, ó ní, “Ǹjẹ́ nǹkankan wà tí ó ṣòro fún èmi OLUWA láti ṣe bí? O óo rí i bóyá ohun tí mo sọ fún ọ yóo ṣẹ, tabi kò ní ṣẹ.” Mose jáde, ó lọ sọ ohun tí OLUWA sọ fún àwọn ọmọ Israẹli; ó sì mú àwọn aadọrin olórí náà wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. OLUWA sọ̀kalẹ̀ ninu ìkùukùu láti bá Mose sọ̀rọ̀. Ó sì mú lára ẹ̀mí tí ó wà lára Mose, ó fi sára àwọn aadọrin olórí náà. Bí ẹ̀mí náà ti bà lé wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀, ṣugbọn wọn kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ mọ́ lẹ́yìn ọjọ́ náà. Meji ninu àwọn olórí náà: Elidadi ati Medadi, kò bá wọn lọ, wọ́n dúró sinu àgọ́ wọn. Ẹ̀mí Ọlọrun bà lé wọn, wọ́n sì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀. Ọmọkunrin kan sáré wá sọ fún Mose pé Elidadi ati Medadi ń sọ àsọtẹ́lẹ̀. Nígbà náà ni Joṣua, ọmọ Nuni, iranṣẹ Mose, ọ̀kan ninu àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ wí fún Mose pé, “Pa wọ́n lẹ́nu mọ́.” Mose dáhùn pé, “Kí ló dé tí o fi ń jowú nítorí mi? Inú mi ìbá dùn bí OLUWA bá lè fún gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ ní ẹ̀mí rẹ̀ kí wọ́n sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀.” Lẹ́yìn náà Mose ati àwọn aadọrin olórí náà pada sí ibùdó. OLUWA sì rán ìjì ńlá jáde, ó kó àwọn ẹyẹ kéékèèké kan wá láti etí òkun, wọ́n bà sí ẹ̀gbẹ́ ibùdó àwọn ọmọ Israẹli. Wọn kò fò ju igbọnwọ meji lọ sílẹ̀, wọ́n wà ní ẹ̀yìn ibùdó káàkiri ní ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ kan. Àwọn eniyan náà kó ẹyẹ ní ọ̀sán ati ní òru, ẹni tí ó kó kéré jù ni ó kó òṣùnwọ̀n homeri mẹ́wàá. Wọ́n sì sá wọn sílẹ̀ yí ibùdó wọn ká. Nígbà tí wọn ń jẹ ẹran náà, ibinu OLUWA ru sí wọn, ó sì mú kí àjàkálẹ̀ àrùn jà láàrin wọn. Wọ́n pe orúkọ ibẹ̀ ní Kiburotu Hataafa, èyí tí ó túmọ̀ sí ibojì ojúkòkòrò, nítorí níbẹ̀ ni wọ́n sin òkú àwọn tí wọ́n ṣe ojúkòkòrò ẹran sí. Àwọn eniyan náà sì ṣí kúrò níbẹ̀ lọ sí Haserotu, wọ́n sì pàgọ́ wọn sibẹ. Miriamu ati Aaroni sọ̀rọ̀ òdì sí Mose nítorí pé ó fẹ́ ọmọbinrin ará Kuṣi ní iyawo. Wọn ń wí pé, “Ṣé Mose nìkan ni OLUWA ti lò láti bá eniyan sọ̀rọ̀ ni? Ṣé kò ti lo àwa náà rí?” OLUWA sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tí wọn ń sọ. Mose ni ó jẹ́ oníwà ìrẹ̀lẹ̀ jù ninu gbogbo ẹni tí ó wà láyé. Lójijì, OLUWA sọ fún Mose, Aaroni, ati Miriamu pé, “Ẹ wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.” OLUWA sì dúró ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ ninu ọ̀wọ̀n ìkùukùu, ó sì pe Aaroni ati Miriamu, àwọn mejeeji sì jáde siwaju. OLUWA sì sọ fún wọn pé, “Ẹ gbọ́ ohun tí n óo sọ yìí: Nígbà tí àwọn wolii wà láàrin yín, èmi a máa fi ara hàn wọ́n ninu ìran, èmi a sì máa bá wọn sọ̀rọ̀ lójú àlá. Ṣugbọn ti Mose, iranṣẹ mi yàtọ̀. Mo ti fi ṣe alákòóso àwọn eniyan mi. Lojukooju ni èmi í máa bá a sọ̀rọ̀; ọ̀rọ̀ ketekete sì ni, kì í ṣe àdììtú ọ̀rọ̀. Kódà, òun a máa rí ìrísí OLUWA. Kí ló dé tí ẹ kò fi bẹ̀rù ati sọ̀rọ̀ òdì sí i?” Inú sì bí OLUWA sí àwọn mejeeji, ó sì kúrò lọ́dọ̀ wọn. Bí ọ̀wọ̀n ìkùukùu tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ ti gbéra sókè ni ẹ̀tẹ̀ bo Miriamu, ó sì funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Nígbà tí Aaroni wo Miriamu ó ri wí pé ó ti di adẹ́tẹ̀. Aaroni sì wí fún Mose pe, “Olúwa mi, jọ̀wọ́ má jẹ́ kí á jìyà ẹ̀ṣẹ̀ ìwà àìgbọ́n wa. Má jẹ́ kí ó dàbí ọmọ tí ó ti kú kí á tó bí i, tí apákan ara rẹ̀ sì ti jẹrà.” Mose ké pe Ọlọrun kí ó wò ó sàn. OLUWA sì dáhùn pé, “Bí baba rẹ̀ bá tutọ́ sí i lójú, ṣé ìtìjú rẹ̀ kò ha ní wà lára rẹ̀ fún ọjọ́ meje ni? Nítorí náà, jẹ́ kí wọ́n fi sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọ̀sẹ̀ kan, lẹ́yìn náà, kí wọ́n mú un pada.” Wọ́n sì fi Miriamu sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọjọ́ meje, àwọn eniyan náà kò sì kúrò níbẹ̀ títí di ìgbà tí wọ́n mú un pada. Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣí kúrò ni Haserotu, wọ́n sì pa àgọ́ wọn sí aṣálẹ̀ Parani. OLUWA sọ fún Mose pé, “Rán amí lọ wo ilẹ̀ Kenaani tí mo fún àwọn ọmọ Israẹli. Ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ó bá jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ni kí o rán.” Mose bá rán àwọn ọkunrin tí wọ́n jẹ́ olórí ninu ẹ̀yà wọn lọ, láti aṣálẹ̀ Parani. Orúkọ wọn nìwọ̀nyí: láti inú ẹ̀yà Reubẹni, ó rán Ṣamua ọmọ Sakuri; láti inú ẹ̀yà Simeoni, ó rán Ṣafati ọmọ Hori; láti inú ẹ̀yà Juda, ó rán Kalebu, ọmọ Jefune; láti inú ẹ̀yà Isakari, ó rán Igali, ọmọ Josẹfu; láti inú ẹ̀yà Efuraimu, ó rán Hoṣea ọmọ Nuni; láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, ó rán Paliti, ọmọ Rafu; láti inú ẹ̀yà Sebuluni, ó rán Gadieli, ọmọ Sodi; láti inú ẹ̀yà Josẹfu, tí í ṣe ẹ̀yà Manase, ó rán Gadi, ọmọ Susi; láti inú ẹ̀yà Dani, ó rán Amieli, ọmọ Gemali; láti inú ẹ̀yà Aṣeri, ó rán Seturu, ọmọ Mikaeli; láti inú ẹ̀yà Nafutali, ó rán Nahibi ọmọ Fofisi; láti inú ẹ̀yà Gadi, ó rán Geueli ọmọ Maki. Orúkọ àwọn ọkunrin tí Mose rán láti lọ ṣe amí ilẹ̀ náà nìyí. Mose sì yí orúkọ Hoṣea ọmọ Nuni pada sí Joṣua. Mose rán wọn láti lọ ṣe amí ilẹ̀ náà. Kí wọ́n tó lọ, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gba ọ̀nà ìhà àríwá, kí ẹ tọ̀ ọ́ lọ sí ìhà gúsù ilẹ̀ Kenaani, kí ẹ wá lọ sí àwọn orí òkè. Ẹ wo irú ilẹ̀ tí ilẹ̀ Kenaani jẹ́, àwọn eniyan mélòó ló ń gbé ibẹ̀ ati pé báwo ni wọ́n ṣe lágbára sí. Ẹ ṣe akiyesi bóyá ilẹ̀ náà dára tabi kò dára, ati pé bóyá àwọn eniyan ibẹ̀ ń gbé inú àgọ́ ninu ìlú tí ó tẹ́jú tabi ìlú olódi ni ìlú wọn. Ẹ wò bóyá ilẹ̀ náà jẹ́ ilẹ̀ ọlọ́ràá tí ó lẹ́tù lójú, ẹ wò ó bóyá igi wà níbẹ̀ tabi kò sí. Ẹ múra gírí kí ẹ sì mú ninu èso ilẹ̀ náà bọ̀.” (Àkókò náà sì jẹ́ àkókò àkọ́so àjàrà.) Àwọn eniyan náà lọ, wọ́n sì wo ilẹ̀ náà láti aṣálẹ̀ Sini títí dé Rehobu ati ni ẹ̀bá ibodè Hamati. Wọ́n gba ìhà gúsù gòkè lọ sí Heburoni, níbi tí àwọn ẹ̀yà Ahimani, ati ti Ṣeṣai ati ti Talimai, àwọn òmìrán ọmọ Anaki ń gbé. (A ti tẹ Heburoni dó ní ọdún meje ṣáájú Soani ní ilẹ̀ Ijipti.) Nígbà tí wọ́n dé àfonífojì Eṣikolu, wọn gé ṣiiri àjàrà kan tí ó ní èso. Ṣiiri àjàrà yìí tóbi tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé àwọn meji ni wọ́n fi ọ̀pá gbé e. Wọ́n sì mú èso pomegiranate ati èso ọ̀pọ̀tọ́ wá pẹlu. Wọ́n sọ ibẹ̀ ní àfonífojì Eṣikolu, nítorí ibẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli ti gé ìtì èso àjàrà. Lẹ́yìn tí wọ́n ti wo ilẹ̀ náà fún ogoji ọjọ́, àwọn amí náà pada. Wọn tọ Mose, Aaroni, ati àwọn ọmọ Israẹli lọ ní Kadeṣi ní aṣálẹ̀ Parani. Wọ́n sọ gbogbo ohun tí ojú wọn rí, wọ́n sì fi èso tí wọ́n mú wá hàn wọ́n. Wọ́n sọ fún Mose pé, “A ti wo ilẹ̀ tí ẹ rán wa lọ wò, a sì rí i pé ó jẹ́ ilẹ̀ tí ó dára, tí ó kún fún wàrà ati fún oyin ni. Ó lẹ́tù lójú lọpọlọpọ; èso inú rẹ̀ nìwọ̀nyí. Ṣugbọn àwọn eniyan tí ń gbé inú rẹ̀ lágbára, ìlú ńláńlá tí wọ́n sì mọ odi yíká ni ìlú wọn. Ohun tí ó wá burú ju gbogbo rẹ̀ lọ ni pé, a rí àwọn òmìrán ọmọ Anaki níbẹ̀. Àwọn ará Amaleki ń gbé ìhà gúsù ilẹ̀ náà. Àwọn ará Hiti, ará Jebusi ati àwọn ará Amori ń gbé àwọn agbègbè olókè. Àwọn ará Kenaani sì ń gbé lẹ́bàá òkun ati ní agbègbè Jọdani.” Ṣugbọn Kalebu pa àwọn eniyan náà lẹ́nu mọ́ níwájú Mose, ó ní, “Ẹ jẹ́ kí á lọ nisinsinyii láti gba ilẹ̀ náà, nítorí a lágbára tó láti borí àwọn eniyan náà.” Àwọn amí yòókù ní, “Rárá o! A kò lágbára tó láti gbógun ti àwọn eniyan náà, wọ́n lágbára jù wá lọ.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe mú ìròyìn burúkú wá nípa ilẹ̀ tí wọ́n lọ wò. Wọ́n ní, “Ilẹ̀ tí ń jẹ àwọn eniyan inú rẹ̀ ni ilẹ̀ náà, gbogbo àwọn tí a rí níbẹ̀ ṣígbọnlẹ̀. A tilẹ̀ rí àwọn òmìrán ọmọ Anaki níbẹ̀, bíi tata ni a rí níwájú wọn.” Gbogbo àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí ké, wọn sì fi gbogbo òru ọjọ́ náà sọkún. Gbogbo wọn ń kùn sí Mose ati Aaroni pé, “Ó sàn fún wa kí á kúkú kú sí Ijipti tabi ní aṣálẹ̀ yìí. Kí ló dé tí OLUWA fi ń mú wa lọ sí ilẹ̀ náà kí àwọn ọ̀tá wa lè pa wá, kí wọ́n sì kó àwọn aya ati àwọn ọmọ wa lẹ́rú. Ǹjẹ́ kò ní sàn fún wa kí á pada sí Ijipti?” Wọ́n sọ fún ara wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á yan olórí, kí á pada sí Ijipti.” Mose ati Aaroni bá dojúbolẹ̀ níwájú àwọn eniyan náà. Joṣua ọmọ Nuni ati Kalebu ọmọ Jefune tí wọ́n wà lára àwọn amí fa aṣọ wọn ya láti fi ìbànújẹ́ wọn hàn. Wọ́n sọ fún ìjọ eniyan Israẹli pé, “Ilẹ̀ tí a lọ wò náà jẹ́ ilẹ̀ tí ó dára lọpọlọpọ. Bí inú OLUWA bá dùn sí wa, yóo mú wa dé ilẹ̀ náà, yóo sì fún wa; àní ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati fún oyin, ilẹ̀ ọlọ́ràá tí ó lẹ́tù lójú. Ẹ má lòdì sí OLUWA, ẹ má sì bẹ̀rù àwọn eniyan tí ń gbé ilẹ̀ náà. A óo ṣẹgun wọn, nítorí kò sí ààbò fún wọn mọ́. OLUWA wà pẹlu wa, ẹ má bẹ̀rù.” Bí àwọn eniyan náà ti ń gbèrò láti sọ wọ́n lókùúta pa ni wọ́n rí i tí ògo OLUWA fara hàn ní Àgọ́ Àjọ. OLUWA sọ fún Mose pé, “Àwọn eniyan wọnyi yóo ti kọ̀ mí sílẹ̀ pẹ́ tó. Yóo ti pẹ́ tó kí wọ́n tó máa gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrin wọn? N óo rán àjàkálẹ̀ àrùn láti pa gbogbo wọn run, n óo sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀, ṣugbọn n óo sọ ọ́ di baba orílẹ̀-èdè tí yóo pọ̀ ju àwọn wọnyi lọ, tí yóo sì lágbára jù wọ́n lọ.” Mose bá sọ fún OLUWA pé, “Ní ààrin àwọn ará Ijipti ni o ti mú àwọn eniyan wọnyi jáde pẹlu agbára. Nígbà tí wọn bá sì gbọ́ ohun tí o ṣe sí wọn, wọn yóo sọ fún àwọn eniyan tí ń gbé ilẹ̀ yìí. Àwọn eniyan wọnyi sì ti gbọ́ pé ìwọ OLUWA wà pẹlu wa ati pé à máa rí ọ ninu ìkùukùu nígbà tí o bá dúró lókè ibi tí a wà; nígbà tí o bá ń lọ níwájú wa ninu ọ̀wọ̀n ìkùukùu lọ́sàn-án, ati ninu ọ̀wọ̀n iná lóru. Nisinsinyii, bí o bá pa àwọn eniyan yìí bí ẹni tí ó pa ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo, àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti gbọ́ òkìkí rẹ yóo wí pé; o pa àwọn eniyan rẹ ninu aṣálẹ̀ nítorí pé o kò lè kó wọn dé ilẹ̀ tí o ti ṣèlérí fún wọn. Nítorí náà OLUWA, èmi bẹ̀ Ọ́, fi agbára ńlá rẹ hàn gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ pé, ‘OLUWA kì í tètè bínú, àánú rẹ̀ sì pọ̀. A máa dárí ẹ̀ṣẹ̀ ati àìṣedéédé ji eniyan, ṣugbọn kì í jẹ́ kí ẹlẹ́bi lọ láìjìyà. A máa fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ títí dé ìran kẹta ati ikẹrin.’ Nisinsinyii OLUWA, mo bẹ̀ Ọ́, ro títóbi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, kí o dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan yìí jì wọ́n bí o ti ń dáríjì wọ́n láti ìgbà tí wọ́n ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.” OLUWA dáhùn pé, “Mo ti dáríjì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bẹ̀ rẹ. Ṣugbọn nítòótọ́, níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè, tí ògo mi sì kún ayé, àwọn eniyan wọnyi, tí wọ́n ti rí ògo mi ati àwọn iṣẹ́ ìyanu tí mo ṣe ní Ijipti ati ninu aṣálẹ̀, ṣugbọn tí wọ́n ti dán mi wò nígbà mẹ́wàá, tí wọ́n sì ṣàìgbọràn sí mi, ẹnikẹ́ni ninu wọn kò ní dé ilẹ̀ tí mo ti ṣe ìlérí fún àwọn baba wọn. Ẹyọ kan ninu àwọn tí wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀ wọnyi kò ní débẹ̀. Ṣugbọn nítorí pé iranṣẹ mi, Kalebu, ní ẹ̀mí tí ó yàtọ̀, ó sì jẹ́ olóòótọ́ sí mi, n óo mú un dé ilẹ̀ tí ó lọ wò, ilẹ̀ náà yóo sì jẹ́ ti àwọn ọmọ rẹ̀. Nítorí pé àwọn Amaleki ati ará Kenaani ń gbé àfonífojì, ní ọ̀la, ẹ gbéra, kí ẹ gba ọ̀nà Òkun Pupa lọ sinu aṣálẹ̀.” OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé, “Yóo ti pẹ́ tó tí àwọn eniyan burúkú wọnyi yóo fi máa kùn sí mi? Mo ti gbọ́ gbogbo kíkùn tí wọn ń kùn sí mi. Nisinsinyii, sọ fún wọn pé, ‘Bí mo tì wà láàyè, n óo ṣe yín gẹ́gẹ́ bí ẹ ti wí. Ẹ óo kú ninu aṣálẹ̀ yìí; gbogbo yín; ohun tí ó ṣẹ̀ láti ẹni ogún ọdún lọ sókè, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ kùn sí mi. Ẹnikẹ́ni ninu yín kò ní wọ ilẹ̀ tí mo ti búra pé yóo jẹ́ ibùgbé yín, àfi Kalebu ọmọ Jefune ati Joṣua, ọmọ Nuni. Ṣugbọn àwọn ọmọ yín tí ẹ sọ pé ogun yóo kó, ni n óo mú dé ilẹ̀ náà; ilẹ̀ tí ẹ kọ̀ sílẹ̀ yóo sì jẹ́ tiwọn. Ṣugbọn ní tiyín, ẹ ó kú ninu aṣálẹ̀ níhìn-ín. Àwọn ọmọ yín yóo rìn káàkiri ninu aṣálẹ̀ fún ogoji ọdún, gẹ́gẹ́ bí ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún aiṣododo yín, títí gbogbo yín yóo fi kú tán. Ẹ óo sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín fún ogoji ọdún. Ọdún kọ̀ọ̀kan yóo dípò ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ninu ogoji ọjọ́ tí àwọn amí fi wo ilẹ̀ náà. Ẹ óo rí ibinu mi. Mo ti ṣe ìlérí pé n óo ṣe àwọn nǹkan wọnyi sí ẹ̀yin eniyan burúkú, tí ẹ̀ ń lòdì sí mi wọnyi. Gbogbo yín ni yóo kú ninu aṣálẹ̀ yìí. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ” OLUWA bá mú àwọn tí Mose rán lọ wo ilẹ̀ náà tí wọ́n sì mú ìròyìn burúkú wá, àwọn tí wọ́n mú kí àwọn eniyan náà kùn sí Mose, ó bá fi àrùn burúkú pa wọ́n. Joṣua ọmọ Nuni ati Kalebu ọmọ Jefune nìkan ni wọ́n yè ninu àwọn amí mejila náà. Nígbà tí Mose sọ ohun tí OLUWA sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n káàánú gidigidi. Wọ́n bá gbéra ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, wọ́n lọ sí agbègbè olókè, wọ́n sì wí pé, “Nítòótọ́ a ti dẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn nisinsinyii a ti ṣetán láti lọ gba ilẹ̀ náà tí OLUWA ti sọ nípa rẹ̀ fún wa.” Mose dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe àìgbọràn sí àṣẹ OLUWA nisinsinyii? Ohun tí ẹ fẹ́ ṣe yìí kò ní yọrí sí rere. Ẹ má lọ nítorí OLUWA kò ní wà pẹlu yín, àwọn ọ̀tá yín yóo sì ṣẹgun yín. Ẹ óo kú nígbà tí ẹ bá ń bá àwọn ará Amaleki ati Kenaani jagun. OLUWA kò ní wà pẹlu yín nítorí pé ẹ ti ṣe àìgbọràn sí i.” Sibẹsibẹ àwọn eniyan náà lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Àpótí Majẹmu OLUWA tabi Mose kò kúrò ní ibùdó. Àwọn ará Amaleki ati Kenaani tí ń gbé ibẹ̀ bá wọn jagun, wọ́n ṣẹgun àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì lé wọn títí dé Horima. OLUWA sọ fún Mose pé, “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, bí ẹ bá dé ilẹ̀ tí mo fún yín láti máa gbé, tí ẹ bá mú ninu agbo ẹran yín láti fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA tabi láti fi san ẹ̀jẹ́, tabi láti fi rú ẹbọ àtinúwá, tabi ẹbọ ní ọjọ́ àjọ yín, láti pèsè òórùn dídùn fún OLUWA; ẹni tí ó fẹ́ rúbọ yóo tọ́jú ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi idamẹrin òṣùnwọ̀n hini òróró kan pò fún ẹbọ ohun jíjẹ; ati idamẹrin òṣùnwọ̀n hini ọtí fún ẹbọ ohun mímu, pẹlu ẹbọ sísun tabi ẹbọ ọ̀dọ́ aguntan kan. Fún ẹbọ àgbò, yóo wá ìdámárùn-ún òṣùnwọ̀n efa ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi ìdámẹ́ta òṣùnwọ̀n hini òróró kan pò wá, pẹlu ìdámẹ́ta òṣùnwọ̀n hini ọtí fún ẹbọ ohun mímu; yóo jẹ́ òórùn dídùn sí OLUWA. Bí ẹ bá mú akọ mààlúù wá fún ọrẹ ẹbọ sísun, tabi fún ìrúbọ láti san ẹ̀jẹ́ tabi fún ẹbọ alaafia sí OLUWA, ẹ óo mú ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta òṣùnwọ̀n efa ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi ìdajì òṣùnwọ̀n hini òróró kan pò wá, pẹlu ìdajì òṣùnwọ̀n hini ọtí waini kan, fún ẹbọ ohun mímu, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun. Yóo jẹ́ òórùn dídùn sí OLUWA. “Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe pẹlu akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan tabi àgbò kọ̀ọ̀kan tabi ọ̀dọ́ àgbò kọ̀ọ̀kan tabi ọmọ aguntan kọ̀ọ̀kan. Ẹ óo mú àwọn nǹkan tí a kà sílẹ̀ wá pẹlu olukuluku ẹran tí ẹ bá fẹ́ fi rúbọ. Nígbà tí àwọn ọmọ onílẹ̀ bá fẹ́ rú ẹbọ sísun, tí ó jẹ́ òórùn dídùn sí OLUWA, wọn óo tẹ̀lé ìlànà yìí. Bí àjèjì kan tí ń gbé ààrin yín, tabi ẹnikẹ́ni tí ó wà láàrin yín bá fẹ́ rú ẹbọ sísun, tí ó jẹ́ òórùn dídùn sí OLUWA, irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóo tẹ̀lé ìlànà tí mo fi lélẹ̀ fun yín, ìlànà yìí yóo wà fún ìrandíran yín. Ìlànà kan náà ni yóo wà fún gbogbo ìjọ eniyan Israẹli ati àwọn àjèjì tí wọ́n wà láàrin yín. Ìlànà yìí yóo wà títí lae ní ìrandíran yín. Bí ẹ ti rí níwájú OLUWA, bẹ́ẹ̀ náà ni àjèjì tí ó wà láàrin yín rí. Òfin ati ìlànà kan náà ni yóo wà fún ẹ̀yin ati àjèjì tí ń gbé pẹlu yín.” OLUWA sọ fún Mose pé, “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí mò ń mu yín lọ, tí ẹ bá jẹ ninu oúnjẹ ilẹ̀ náà, ẹ óo mú ọrẹ wá fún OLUWA. Ẹ mú ọrẹ wá fún OLUWA lára àwọn àkàrà tí ẹ kọ́kọ́ ṣe gẹ́gẹ́ bí ọrẹ láti ibi ìpakà. Lára àwọn àkàrà tí ẹ bá kọ́kọ́ ṣe ni ẹ óo máa mú wá fi ṣe ọrẹ fún OLUWA ní ìrandíran yín. “Ṣugbọn bí ẹ bá kọ̀, tí ẹ kò pa àwọn òfin wọnyi, tí OLUWA fún Mose mọ́, àní àwọn òfin tí OLUWA tipasẹ̀ Mose fún yín, láti ọjọ́ tí OLUWA ti fún un ní òfin títí lọ, ní ìrandíran yín; bí gbogbo ìjọ eniyan Israẹli bá ṣẹ̀, láìmọ̀, wọn óo fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan rú ẹbọ sísun, olóòórùn dídùn sí OLUWA, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu, ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà. Alufaa yóo ṣe ètùtù fún gbogbo ìjọ eniyan Israẹli, a óo sì dáríjì wọ́n nítorí pé àṣìṣe ni; wọ́n sì ti mú ẹbọ sísun ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wá fún OLUWA nítorí àṣìṣe wọn. A óo dáríjì gbogbo ìjọ eniyan Israẹli ati àwọn àjèjì tí ń gbé ààrin wọn nítorí pé gbogbo wọn ni ó lọ́wọ́ sí àṣìṣe náà. “Bí ẹnikẹ́ni bá ṣẹ̀ láìmọ̀, yóo fi abo ewúrẹ́ ọlọ́dún kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Alufaa yóo ṣe ètùtù niwaju pẹpẹ fún olúwarẹ̀ tí ó ṣe àṣìṣe, a óo sì dáríjì í. Òfin kan náà ni ó wà fún gbogbo àwọn tí o bá ṣẹ̀ láìmọ̀, ìbáà ṣe ọmọ Israẹli tabi àjèjì tí ń gbé láàrin ilẹ̀ Israẹli. “Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀ọ́nmọ̀ ṣẹ̀, kò náání OLUWA, ìbáà ṣe ọmọ Israẹli tabi àjèjì tí ń gbé láàrin wọn, a óo yọ olúwarẹ̀ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀; nítorí pé ó pẹ̀gàn ọ̀rọ̀ OLUWA, kò sì pa òfin rẹ̀ mọ́, a óo yọ ọ́ kúrò patapata, ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ yóo sì wà lórí rẹ̀.” Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli wà ninu aṣálẹ̀, wọ́n rí ọkunrin kan tí ń ṣẹ́gi ní ọjọ́ ìsinmi; àwọn tí wọ́n rí i mú un wá sọ́dọ̀ Mose ati Aaroni ati gbogbo ìjọ eniyan. Wọ́n fi sí àhámọ́ nítorí wọn kò tíì mọ ohun tí wọn yóo ṣe sí i. OLUWA sọ fún Mose pé, “Pípa ni kí ẹ pa ọkunrin náà, kí gbogbo ìjọ eniyan sọ ọ́ lókùúta pa lẹ́yìn ibùdó.” Gbogbo ìjọ eniyan bá mú un lọ sẹ́yìn ibùdó, wọ́n sì sọ ọ́ lókùúta pa gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. OLUWA sọ fún Mose pé, “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọ́n ṣe oko jọnwọnjọnwọn sí etí aṣọ wọn ní ìrandíran wọn; kí wọ́n sì ta okùn aláwọ̀ aró mọ oko jọnwọnjọnwọn kọ̀ọ̀kan. Èyí ni ẹ óo máa wọ̀, tí yóo máa rán yín létí àwọn òfin OLUWA, kí ẹ lè máa pa wọ́n mọ́; kí ẹ má fi ìwọ̀ra tẹ̀lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn yín ati ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú yín. Kí ẹ lè máa ranti àwọn òfin mi, kí ẹ máa pa wọ́n mọ́, kí ẹ sì jẹ́ ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún Ọlọrun yín. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín tí ó ko yín jáde wa láti ilẹ̀ Ijipti, láti jẹ́ Ọlọrun yín: Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.” Kora ọmọ Iṣari láti inú ìdílé Kohati ọmọ Lefi, pẹlu Datani ati Abiramu àwọn ọmọ Eliabu, pẹlu Ooni ọmọ Peleti láti inú ẹ̀yà Reubẹni gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n kó aadọtaleerugba (250) ọkunrin tí wọ́n jọ jẹ́ olórí ati olókìkí ninu àwọn ọmọ Israẹli sòdí láti dìtẹ̀ mọ́ Mose. Wọ́n dojú kọ Mose ati Aaroni, wọ́n ní, “Ẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí kọjá ààyè yín, nítorí pé olukuluku àwọn ọmọ Israẹli ni ó jẹ́ ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún OLUWA, OLUWA sì ń bẹ láàrin wọn. Kí ló dé tí ẹ̀yin gbé ara yín ga ju gbogbo àwọn eniyan OLUWA lọ?” Nígbà tí Mose gbọ́, ó dojúbolẹ̀, Ó sì sọ fún Kora ati àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ pé, “Ní ọ̀la OLUWA yóo fi ẹni tí í ṣe tirẹ̀ tí ó jẹ́ ẹni mímọ́ hàn. Ẹni tí OLUWA bá sì yàn ni yóo mú kí ó súnmọ́ òun. Ní ọ̀la ìwọ ati àwọn ẹgbẹ́ rẹ, ẹ mú àwo turari, kí ẹ fi iná sinu wọn, kí ẹ sì gbé wọn lọ siwaju OLUWA. Ẹni tí OLUWA bá yàn ni yóo jẹ́ ẹni mímọ́; ẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí kọjá ààyè yín, ẹ̀yin ọmọ Lefi!” Mose bá kọjú sí Kora, ó ní: “Ẹ gbọ́ ẹ̀yin ọmọ Lefi! Ṣé nǹkan kékeré ni, pé Ọlọrun Israẹli yà yín sọ́tọ̀ láàrin àwọn ọmọ Israẹli láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn ninu Àgọ́ Àjọ OLUWA, ati fún ìjọ eniyan Israẹli? OLUWA ti fún ẹ̀yin ati àwọn ọmọ Lefi yòókù ní anfaani yìí, ṣugbọn nisinsinyii, ẹ̀ ń ṣe ojú kòkòrò sí iṣẹ́ alufaa. Ṣé ẹ kò mọ̀ pé OLUWA ni ìwọ ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ ń ṣọ̀tẹ̀ sí, nígbà tí ẹ̀ ń fi ẹ̀sùn kan Aaroni? Ta ni Aaroni tí ẹ̀yin ń fi ẹ̀sùn kàn?” Mose bá ranṣẹ lọ pe Datani ati Abiramu, àwọn ọmọ Eliabu, ṣugbọn wọ́n kọ̀ wọn kò wá. Wọ́n ní, “O mú wa wá láti ilẹ̀ ọlọ́ràá Ijipti tí ó kún fún wàrà ati fún oyin, o fẹ́ wá pa wá sinu aṣálẹ̀ yìí, sibẹ kò tó ọ, o tún fẹ́ sọ ara rẹ di ọba lórí gbogbo wa. O kò tíì kó wa dé ilẹ̀ tí ó lọ́ràá tí ó kún fún wàrà ati oyin, tabi kí o fún wa ní ọgbà àjàrà ati oko. Ṣé o fẹ́ fi júújúú bo àwọn eniyan wọnyi lójú ni, a kò ní dá ọ lóhùn.” Mose bínú gidigidi, ó sì sọ fún OLUWA pé, “OLUWA, má ṣe gba ẹbọ àwọn eniyan wọnyi. N kò ṣe ibi sí ẹnikẹ́ni ninu wọn bẹ́ẹ̀ ni ń kò gba kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹnikẹ́ni wọn.” Mose bá sọ fún Kora pé, “Ní ọ̀la kí ìwọ ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ wá siwaju Àgọ́ Àjọ. Aaroni pẹlu yóo wà níbẹ̀. Kí olukuluku yín ati Aaroni pẹlu mú àwo turari rẹ̀, kí ẹ sì fi turari sí i láti rúbọ sí OLUWA. Gbogbo rẹ̀ yóo jẹ́ aadọtaleerugba (250) àwo turari.” Olukuluku wọn sì mú àwo turari tirẹ̀, wọ́n fi ẹ̀yinná ati turari sí i, wọ́n sì dúró ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ pẹlu Mose ati Aaroni. Kora kó gbogbo ìjọ eniyan náà jọ sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ láti dojú kọ Mose ati Aaroni; Ògo OLUWA sì farahàn, àwọn eniyan náà sì rí i. OLUWA sì sọ fún Mose ati Aaroni pé: “Ẹ bọ́ sí apá kan kí n lè rí ààyè pa àwọn eniyan náà run ní ìṣẹ́jú kan.” Mose ati Aaroni bá dojúbolẹ̀, wọ́n gbadura sí OLUWA, pé, “Ọlọrun, ìwọ ni orísun ìyè, ìwọ yóo ha tìtorí ẹ̀ṣẹ̀ ẹnìkan bínú sí gbogbo ìjọ eniyan bí?” OLUWA bá dá Mose lóhùn pé, “Sọ fún àwọn eniyan náà kí wọ́n kúrò ní agbègbè àgọ́ àwọn Kora ati Datani ati Abiramu.” Mose bá dìde pẹlu àwọn àgbààgbà Israẹli, wọ́n lọ sọ́dọ̀ Datani ati Abiramu. Ó sì sọ fún àwọn eniyan pé, “Ẹ kúrò ní agbègbè àgọ́ àwọn ọkunrin burúkú wọnyi, kí ẹ má sì fọwọ́ kan nǹkankan tí ó jẹ́ tiwọn, kí ẹ má baà pín ninu ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” Àwọn eniyan náà bá kúrò ní agbègbè àgọ́ àwọn Kora ati Datani ati Abiramu. Datani ati Abiramu pẹlu aya ati àwọn ọmọ wọn jáde wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ wọn. Mose sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Nisinsinyii ni ẹ óo mọ̀ pé èmi kọ́ ni mo yan ara mi ṣugbọn OLUWA ni ó rán mi láti ṣe gbogbo ohun tí mò ń ṣe. Bí àwọn ọkunrin wọnyi bá kú ikú tí kò mú ìbẹ̀rù lọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun, a jẹ́ wí pé kì í ṣe OLUWA ni ó rán mi. Ṣugbọn bí OLUWA bá ṣe ohun tí etí kò gbọ́ rí, tí ilẹ̀ bá yanu tí ó gbé wọn mì pẹlu àwọn eniyan wọn ati àwọn ohun ìní wọn, tí wọn sì bọ́ sinu ibojì láàyè, ẹ óo mọ̀ pé wọ́n ti kọ OLUWA sílẹ̀.” Ní kété tí Mose parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ilẹ̀ tí wọ́n dúró lé lórí là sí meji, ó yanu, ó sì gbé wọn mì, ati àwọn ati ìdílé wọn, ati ohun ìní wọn. Ilẹ̀ sì gbé Kora mì pẹlu àwọn eniyan rẹ̀ ati gbogbo ohun ìní wọn. Gbogbo wọn, ati ohun ìní wọn, ati àwọn eniyan wọn, lọ sí ipò òkú láàyè, ilẹ̀ panudé, wọ́n sì ṣègbé kúrò láàrin ìjọ eniyan Israẹli. Àwọn ọmọ Israẹli tí ó wà níbẹ̀ sì sálọ nígbà tí wọn gbọ́ igbe wọn. Wọ́n bẹ̀rù kí ilẹ̀ má baà gbé àwọn náà mì. OLUWA sì rán iná láti run àwọn aadọtaleerugba (250) ọkunrin tí wọn mú àwo turari wá siwaju Àgọ́ Àjọ. OLUWA sọ fún Mose pé, “Sọ fún Eleasari ọmọ Aaroni, alufaa pé kí ó kó àwọn àwo turari wọ̀n-ọn-nì kúrò láàrin àjókù àwọn eniyan náà. Kí ó sì da iná inú wọn káàkiri jìnnà jìnnà nítorí àwọn àwo turari náà jẹ́ mímọ́. Kí ó mú àwo turari àwọn ọkunrin tí wọ́n kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kí ó fi wọ́n rọ àwo fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ fún ìbòrí pẹpẹ, nítorí níwọ̀n ìgbà tí wọ́n ti mú wọn wá siwaju OLUWA, wọ́n ti di mímọ́. Èyí yóo sì jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli.” Eleasari bá kó àwọn àwo turari náà tí àwọn tí ó jóná fi rú ẹbọ, ó fi wọ́n rọ àwo fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ fún ìbòrí pẹpẹ. Èyí sì jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli pé ẹnikẹ́ni tí kì í bá ṣe ọmọ Aaroni kò gbọdọ̀ wá siwaju pẹpẹ OLUWA láti sun turari, kí ẹni náà má baà dàbí Kora ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti rán Mose pé kí ó sọ fún Eleasari. Ní ọjọ́ keji gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Mose ati Aaroni pé, “Ẹ pa àwọn eniyan OLUWA.” Ó sì ṣe nígbà tí àwọn eniyan náà kó ara wọn jọ láti dojú kọ Mose ati Aaroni, wọn bojúwo ìhà Àgọ́ Àjọ, wọ́n sì rí i tí ìkùukùu bò ó, ògo OLUWA sì farahàn. Mose ati Aaroni lọ dúró níwájú Àgọ́ Àjọ, OLUWA sì sọ fún Mose pé, “Kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan wọnyi kí n lè pa wọ́n run ní ìṣẹ́jú kan.” Mose ati Aaroni bá dojúbolẹ̀. Mose sọ fún Aaroni pé, “Mú àwo turari rẹ, fi ẹ̀yinná sinu rẹ̀ láti orí pẹpẹ kí o sì fi turari sí i. Ṣe kíá, lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan náà láti ṣe ètùtù fún wọn nítorí ibinu OLUWA ti ru, àjàkálẹ̀ àrùn sì ti bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn.” Aaroni sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Mose. Ó mú àwo turari rẹ̀, ó sáré lọ sí ààrin àwọn eniyan náà. Nígbà tí ó rí i pé àjàkálẹ̀ àrùn ti bẹ́ sílẹ̀, ó fi turari sí i, ó sì ṣe ètùtù fún wọn. Aaroni dúró ní ààrin àwọn òkú ati alààyè, àjàkálẹ̀ àrùn náà sì dáwọ́ dúró. Àwọn tí ó kú jẹ́ ẹgbaa meje ó lé ẹẹdẹgbẹrin (14,700) láìka àwọn tí ó kú pẹlu Kora. Nígbà tí àjàkálẹ̀ àrùn náà dáwọ́ dúró, Aaroni pada sọ́dọ̀ Mose lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. OLUWA sọ fún Mose pé, “Gba ọ̀pá mejila láti ọwọ́ àwọn ọmọ Israẹli, ọ̀pá kọ̀ọ̀kan láti ọwọ́ olórí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, kí o sì kọ orúkọ olukuluku sí ara ọ̀pá tirẹ̀. Kọ orúkọ Aaroni sí ọ̀pá tí ó wà fún ẹ̀yà Lefi, nítorí pé ọ̀pá kan ni yóo wà fún olórí kọ̀ọ̀kan. Kí o kó wọn sílẹ̀ níwájú Àpótí Ẹ̀rí ninu Àgọ́ Àjọ mi, níbi tí mo ti máa ń pàdé rẹ. Ọ̀pá ẹni tí mo bá yàn yóo rúwé; bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe fi òpin sí kíkùn tí àwọn ọmọ Israẹli ń kùn sí ọ.” Mose sọ èyí fún àwọn ọmọ Israẹli. Olórí àwọn ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan mú ọ̀pá wọn wá fún Mose, gbogbo rẹ̀ jẹ́ mejila, ọ̀pá Aaroni sì wà ninu wọn. Mose kó gbogbo àwọn ọ̀pá náà siwaju OLUWA ninu Àgọ́ Ẹ̀rí. Nígbà tí ó wọ inú Àgọ́ Ẹ̀rí ní ọjọ́ keji, ó rí i pé ọ̀pá Aaroni tí ó wà fún ẹ̀yà Lefi ti rúwé, ó ti tanná, ó ti so èso alimọndi, èso náà sì ti pọ̀. Mose kó àwọn ọ̀pá náà jáde kúrò níwájú OLUWA, ó kó wọn wá siwaju àwọn ọmọ Israẹli. Gbogbo wọn wò wọ́n, olukuluku àwọn olórí sì mú ọ̀pá tirẹ̀. OLUWA sọ fún Mose, pé, “Dá ọ̀pá Aaroni pada siwaju Àpótí Ẹ̀rí, kí ó lè jẹ́ àmì ìkìlọ̀ fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ Israẹli, kí wọ́n sì lè dẹ́kun kíkùn tí wọn ń kùn sí mi, kí wọ́n má baà kú.” Mose sì ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ fún un. Àwọn ọmọ Israẹli bá sọ fún Mose pé, “A gbé! Gbogbo wa ni a óo ṣègbé. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ ibi mímọ́ yóo kú, ṣé gbogbo wa ni a óo ṣègbé ni?” OLUWA sọ fún Aaroni pé, “Ìwọ, ati àwọn ọmọ rẹ, ati ìdílé baba rẹ ni yóo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n bá dá ní ibi mímọ́. Ṣugbọn ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ nìkan ni yóo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn alufaa bá dá. Pe àwọn eniyan rẹ, àwọn ọmọ Lefi, ẹ̀yà ìdílé baba rẹ, pé kí wọn wà pẹlu rẹ, kí wọ́n sì máa jíṣẹ́ fún ọ nígbà tí ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ bá ń ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Ẹ̀rí. Wọn óo máa jíṣẹ́ fún ọ, wọn óo sì máa ṣe iṣẹ́ wọn ninu Àgọ́ Ẹ̀rí, ṣugbọn wọn kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ọ̀kan ninu àwọn ohun mímọ́ tí ó wà ninu ibi mímọ́ tabi pẹpẹ ìrúbọ, kí gbogbo wọn má baà kú. Wọn óo máa ṣe iṣẹ́ iranṣẹ wọn ninu Àgọ́ Àjọ pẹlu rẹ. Ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe ọmọ Lefi kò gbọdọ̀ bá ọ ṣiṣẹ́. Ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ nìkan ni yóo máa ṣiṣẹ́ ninu ibi mímọ́ ati níbi pẹpẹ, kí ibinu mi má baà wá sórí àwọn ọmọ Israẹli mọ́. Mo ti yan àwọn eniyan rẹ, àwọn ọmọ Lefi, láàrin àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún ọ. Wọ́n jẹ́ ẹ̀bùn fún OLUWA, wọn óo sì máa ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ. Ṣugbọn ìwọ pẹlu àwọn ọmọ rẹ nìkan ni alufaa ti yóo máa ṣiṣẹ́ níbi pẹpẹ ìrúbọ ati níbi aṣọ ìbòjú. Èyí ni yóo jẹ́ iṣẹ́ yín nítorí ẹ̀bùn ni mo fi iṣẹ́ alufaa ṣe fun yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ àwọn ohun mímọ́ yóo kú.” OLUWA sọ fún Aaroni pé, “Mo ti fún ọ ní gbogbo ohun tí ó kù ninu àwọn ohun tí wọ́n bá fi rúbọ sí mi, ati gbogbo ohun tí àwọn ọmọ Israẹli bá yà sọ́tọ̀. Ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ni mo fún gẹ́gẹ́ bi ìpín yín títí lae. Ninu gbogbo ẹbọ mímọ́ tí a kò sun lórí pẹpẹ, ẹbọ ọrẹ, ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, tí wọn ń rú sí mi yóo jẹ́ mímọ́ jùlọ fún ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ. Níbi mímọ́ ni ẹ ti gbọdọ̀ jẹ wọ́n. Àwọn ọkunrin ààrin yín nìkan ni wọ́n gbọdọ̀ jẹ wọ́n nítorí wọ́n jẹ́ ohun mímọ́ jùlọ. “Bákan náà, gbogbo àwọn ọrẹ ẹbọ, ati àwọn ẹbọ fífì tí àwọn ọmọ Israẹli bá mú wá fún mi, yóo jẹ́ tiyín. Mo fún ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ lọkunrin ati lobinrin, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn títí lae. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ mímọ́ ninu wọn lè jẹ ẹ́. “Mo fún ọ ní gbogbo èso àkọ́so tí àwọn ọmọ Israẹli ń mú wá fún mi lọdọọdun, ati òróró tí ó dára jùlọ, ọtí waini tí ó dára jùlọ, ati ọkà. Gbogbo àwọn àkọ́so tí ó pọ́n ní ilẹ̀ náà tí wọn bá mú wá fún OLUWA yóo jẹ́ tìrẹ, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ mímọ́ ninu ilé rẹ lè jẹ ẹ́. “Gbogbo ohun tí àwọn ọmọ Israẹli bá yà sọ́tọ̀ fún mi, tìrẹ ni. “Gbogbo àwọn àkọ́bí eniyan tabi ti ẹranko tí àwọn ọmọ Israẹli bá mú wá fún mi, tìrẹ ni. Ṣugbọn o óo gba owó ìràpadà dípò àkọ́bí eniyan ati ti ẹranko tí ó bá jẹ́ aláìmọ́. Àwọn òbí yóo ra àwọn ọmọ wọn pada nígbà tí wọ́n bá pé ọmọ oṣù kan. Owó ìràpadà wọn jẹ́ ìwọ̀n ṣekeli marun-un. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́, èyí tíí ṣe ogún ìwọ̀n gera ni kí wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Ṣugbọn wọn kò ní ra àwọn àkọ́bí mààlúù, ati ti aguntan ati ti ewúrẹ́ pada, nítorí wọ́n jẹ́ mímọ́. Da ẹ̀jẹ̀ wọn sí ara pẹpẹ kí o sì fi ọ̀rá wọn rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí mi. Gbogbo ẹran wọn jẹ́ tìrẹ, gẹ́gẹ́ bí àyà tí a fì níwájú pẹpẹ, ati itan ọ̀tún ṣe jẹ́ tìrẹ. “Gbogbo àwọn ẹbọ mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli bá mú wá fún mi ni mo fún ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ, lọkunrin ati lobinrin, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn títí lae. Èyí jẹ́ majẹmu pataki tí mo bá ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ dá.” OLUWA sọ fún Aaroni pé, “O kò gbọdọ̀ gba ohun ìní kan tí eniyan lè jogún tabi ilẹ̀ ní Israẹli. Èmi OLUWA ni yóo jẹ́ ìpín ati ìní rẹ láàrin àwọn ọmọ Israẹli.” OLUWA wí pé, “Mo ti fún àwọn ọmọ Lefi ní gbogbo ìdámẹ́wàá tí àwọn ọmọ Israẹli bá mú wá fún mi gẹ́gẹ́ bí ìní wọn fún iṣẹ́ ìsìn wọn ninu Àgọ́ Àjọ. Àwọn ọmọ Israẹli yòókù kò gbọdọ̀ súnmọ́ Àgọ́ Àjọ náà, kí wọn má baà dẹ́ṣẹ̀, kí wọn má baà kú. Ṣugbọn àwọn ọmọ Lefi nìkan ni yóo máa ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ, wọn óo sì ru ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ìlànà ayérayé ni èyí fún arọmọdọmọ yín, wọn kò tún gbọdọ̀ ní ohun ìní kan mọ́, láàrin àwọn ọmọ Israẹli; nítorí pé gbogbo ìdámẹ́wàá tí àwọn ọmọ Israẹli mú wá fún mi ni mo ti fún wọn gẹ́gẹ́ bí ìní. Ìdí sì nìyí tí mo fi sọ fun wọn pé wọn kò lè ní ohun ìní kan mọ́, láàrin àwọn ọmọ Israẹli.” OLUWA rán Mose: kí ó sọ fún àwọn ọmọ Lefi pé, “Nígbà tí ẹ bá gba ìdámẹ́wàá tí OLUWA ti fún yín gẹ́gẹ́ bí ìní yín, ẹ óo san ìdámẹ́wàá ninu rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fún OLUWA. Ọrẹ yìí yóo dàbí ọrẹ ọkà titun, ati ọtí waini titun, tí àwọn àgbẹ̀ ń mú wá fún OLUWA. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú ọrẹ yín wá fún OLUWA ninu ìdámẹ́wàá tí àwọn ọmọ Israẹli bá san fun yín. Ẹ óo mú ọrẹ tí ó jẹ́ ti OLUWA wá fún Aaroni alufaa. Ninu èyí tí ó dára jù ninu àwọn ohun tí ẹ bá gbà ni kí ẹ ti san ìdámẹ́wàá yín. Nígbà tí ẹ bá ti san ìdámẹ́wàá yín lára èyí tí ó dára jù, ìyókù jẹ́ tiyín, gẹ́gẹ́ bí àgbẹ̀ ṣe máa ń kórè oko rẹ̀ lẹ́yìn tí ó ti san ìdámẹ́wàá rẹ̀. Ẹ̀yin ati ẹbí yín lè jẹ ìyókù níbikíbi tí ẹ bá fẹ́, nítorí pé ó jẹ́ èrè yín fún iṣẹ́ tí ẹ̀ ń ṣe ninu Àgọ́ Àjọ. Ẹ kò ní jẹ̀bi nígbà tí ẹ bá jẹ ẹ́, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti san ìdámẹ́wàá ninu èyí tí ó dára jù. Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà sọ ọrẹ mímọ́ àwọn ọmọ Israẹli di àìmọ́ nípa jíjẹ wọ́n láìsan ìdámẹ́wàá wọn. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ óo kú.” OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé, “Ìlànà tí èmi OLUWA fi lélẹ̀ nìyí: Ẹ sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọ́n mú ẹgbọ̀rọ̀ abo mààlúù pupa kan wá. Kò gbọdọ̀ ní àbààwọ́n kankan, wọn kò sì gbọdọ̀ tíì fi ṣiṣẹ́ rí. O óo fún Eleasari alufaa, yóo mú un lọ sí ẹ̀yìn ibùdó, wọn óo sì pa á níbẹ̀ níṣojú rẹ̀. Eleasari yóo gbà ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, yóo fi ìka rẹ̀ wọ́n ọn sí apá ìhà Àgọ́ Àjọ ní ìgbà meje. Kí wọ́n sun ìyókù mààlúù náà: awọ rẹ̀ ati ẹran ara rẹ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ati ìgbẹ́ rẹ̀; kí wọ́n sun gbogbo rẹ̀ níwájú alufaa. Kí alufaa ju igi kedari ati hisopu ati aṣọ pupa sinu iná náà. Lẹ́yìn náà kí ó wẹ̀, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì pada sí ibùdó. Ṣugbọn yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà. Ẹni tí ó sun mààlúù náà gbọdọ̀ wẹ̀ kí ó sì fọ aṣọ rẹ̀, òun náà yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà. Ẹnìkan tí ó jẹ́ mímọ́ yóo kó eérú mààlúù náà jọ sí ibìkan tí ó mọ́ lẹ́yìn ibùdó. Eérú náà ni àwọn ọmọ Israẹli yóo máa lò fún omi ìwẹ̀nùmọ́, fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹni tí ó bá kó eérú náà jọ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, òun náà yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà. Èyí yóo jẹ́ ìlànà fún àwọn ọmọ Israẹli ati fún àwọn àlejò tí ó wà láàrin wọn títí lae. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú yóo jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ meje. Ní ọjọ́ kẹta ati ọjọ́ keje, yóo wẹ ara rẹ̀ pẹlu omi ìwẹ̀nùmọ́, yóo sì di mímọ́. Kò ní di mímọ́ bí kò bá wẹ ara rẹ̀ ní ọjọ́ kẹta ati ọjọ́ keje. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú, tí kò bá fi omi ìwẹ̀nùmọ́ wẹ̀, yóo sọ ibi mímọ́ OLUWA di aláìmọ́. A óo yọ olúwarẹ̀ kúrò láàrin ọmọ Israẹli, nítorí kò fi omi ìwẹ̀nùmọ́ wẹ̀; ó sì jẹ́ aláìmọ́ sibẹ. “Tí ẹnìkan bá kú ninu àgọ́ kan ẹnikẹ́ni tí ó bá wà ninu àgọ́ náà, ati ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ ibẹ̀ yóo di aláìmọ́ fún ọjọ́ meje. Gbogbo ohun èlò tí ó bá wà ninu àgọ́ náà tí wọn kò fi ọmọrí dé di aláìmọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ẹni tí wọ́n fi idà pa, tabi òkú, tabi egungun òkú tabi ibojì òkú ninu pápá yóo di aláìmọ́ fún ọjọ́ meje. “Tí ẹ bá fẹ́ ṣe ìwẹ̀nùmọ́ wọn, ẹnìkan tí ó jẹ́ mímọ́ yóo mú lára eérú mààlúù pupa tí a sun fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, yóo bu omi odò tí ń ṣàn sí i. Lẹ́yìn náà yóo mú hisopu, yóo tì í bọ omi náà, yóo sì fi wọ́n àgọ́ náà ati àwọn ohun èlò tí wọ́n wà ninu rẹ̀ ati àwọn eniyan tí wọ́n wà ninu rẹ̀. Yóo fi wọ́n ẹni tí ó fọwọ́ kan egungun òkú tabi tí ó fọwọ́ kan ẹni tí wọ́n pa, tabi ẹni tí ó kú fúnrarẹ̀, tabi ibojì òkú. Yóo sì bu omi náà wọ́n aláìmọ́ náà ní ọjọ́ kẹta ati ikeje. Ní ọjọ́ keje, yóo wẹ̀, yóo sì di mímọ́. Aláìmọ́ náà yóo fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì wẹ̀ ninu omi, yóo sì di mímọ́ ní ìrọ̀lẹ́. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ aláìmọ́ tí kò sì ṣe ìwẹ̀nùmọ́, yóo jẹ́ aláìmọ́ sibẹ nítorí pé a kò tíì da omi ìwẹ̀nùmọ́ sí i lára. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ sọ ibi mímọ́ OLUWA di aláìmọ́. A óo yọ olúwarẹ̀ kúrò láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Ẹ gbọdọ̀ pa ìlànà yìí mọ́ láti ìrandíran. Ẹni tí ó bá wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ náà sí aláìmọ́ lára gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan omi náà yóo di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà. Ohunkohun tí aláìmọ́ bá fọwọ́ kàn yóo di aláìmọ́, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fọwọ́ kan ohun tí aláìmọ́ náà bá fọwọ́ kàn yóo di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.” Ní oṣù kinni, àwọn ọmọ Israẹli dé aṣálẹ̀ Sini, wọ́n sì ṣe ibùdó wọn sí Kadeṣi. Níbẹ̀ ni Miriamu kú sí, tí wọn sì sin ín sí. Kò sí omi fún àwọn eniyan náà níbi tí wọ́n ṣe ibùdó sí, wọ́n sì kó ara wọn jọ sí Mose ati Aaroni. Wọ́n ń kùn pé: “Ìbá sàn fún wa bí ó bá jẹ́ pé a ti kú nígbà tí àwọn arakunrin wa kú níwájú OLUWA. Kí ló dé tí ẹ fi mú àwọn eniyan OLUWA wá sinu aṣálẹ̀ yìí? Ṣé kí àwa ati àwọn ẹran ọ̀sìn wa lè kú ni? Kí ló dé tí ẹ fi mú wa wá láti Ijipti sí ibi burúkú yìí, kò sí ọkà, kò sí èso ọ̀pọ̀tọ́, tabi èso àjàrà tabi èso pomegiranate, bẹ́ẹ̀ ni kò sí omi mímu.” Mose ati Aaroni kúrò níwájú àwọn eniyan náà, wọ́n lọ dúró ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, wọ́n dojúbolẹ̀, ògo OLUWA sì farahàn. OLUWA sọ fún Mose pé, “Mú ọ̀pá tí ó wà níwájú Àpótí Majẹmu, kí ìwọ ati Aaroni kó àwọn eniyan náà jọ, kí o sọ̀rọ̀ sí àpáta níwájú wọn, àpáta náà yóo sì tú omi jáde. Bẹ́ẹ̀ ni o óo ṣe fún àwọn eniyan náà ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ní omi.” Mose lọ mú ọ̀pá náà níwájú OLUWA gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un. Òun ati Aaroni kó gbogbo àwọn eniyan náà jọ siwaju àpáta náà. Mose sì wí fún wọn pé, “ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀, ṣé kí á mú omi jáde fun yín láti inú àpáta yìí?” Mose bá mu ọ̀pá rẹ̀ ó fi lu àpáta náà nígbà meji, omi sì bẹ̀rẹ̀ sí tú jáde lọpọlọpọ; àwọn eniyan náà ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sì rí omi mu. Ṣugbọn OLUWA bínú sí Mose ati Aaroni, ó ní, “Nítorí pé ẹ kò gbà mí gbọ́, ẹ kò sì fi títóbi agbára mi hàn níwájú àwọn eniyan náà, ẹ̀yin kọ́ ni yóo kó wọn dé ilẹ̀ tí mo ti ṣèlérí láti fún wọn.” Èyí ni omi Meriba, nítorí níbẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli ti ṣe gbolohun asọ̀ pẹlu OLUWA, tí OLUWA sì fi ara rẹ̀ hàn wọ́n pé mímọ́ ni òun. Mose rán oníṣẹ́ láti Kadeṣi sí ọba Edomu pé, “Arakunrin rẹ ni àwa ọmọ Israẹli jẹ́, o sì mọ gbogbo àwọn ìṣòro tí ó ti dé bá wa. Bí àwọn baba ńlá wa ṣe lọ sí ilẹ̀ Ijipti, tí wọ́n sì gbé ibẹ̀ fún ìgbà pípẹ́. Àwọn ará Ijipti lo àwọn baba ńlá wa ati àwa náà ní ìlò ẹrú. Nígbà tí a ké pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́, ó gbọ́ adura wa, ó sì rán angẹli rẹ̀ láti mú wa jáde kúrò ní Ijipti. Nisinsinyii a ti dé Kadeṣi, ìlú kan tí ó wà lẹ́yìn odi agbègbè rẹ. Jọ̀wọ́ gbà wá láàyè kí á gba ilẹ̀ rẹ kọjá. Àwa ati àwọn ẹran ọ̀sìn wa kò ní yà kúrò ní ojú ọ̀nà sinu oko yín tabi ọgbà àjàrà yín. Bẹ́ẹ̀ ni a kò ní mu omi inú kànga yín. Ojú ọ̀nà ni a óo máa tọ̀, a kò ní yà sí ọ̀tún tabi òsì títí tí a óo fi kọjá ilẹ̀ rẹ.” Ṣugbọn àwọn ará Edomu dáhùn pé, “A kò ní jẹ́ kí ẹ gba ilẹ̀ wa kọjá, bí ẹ bá sì fẹ́ kọjá pẹlu agídí, a óo ba yín jagun.” Àwọn ọmọ Israẹli ní, “Ojú ọ̀nà ni a óo máa tọ̀, bí àwa tabi ẹran wa bá tilẹ̀ mu omi yín, a óo sanwó rẹ̀. Ohun kan tí a sá fẹ́ ni pé kí ẹ jẹ́ kí á kọjá.” Àwọn ará Edomu tún dáhùn pé, “Rárá o, ẹ kò lè kọjá.” Wọ́n sì jáde pẹlu ọpọlọpọ ọmọ ogun ati agbára ogun láti lọ dojú ìjà kọ àwọn ọmọ Israẹli. Nígbà tí àwọn ará Edomu kò jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli gba ilẹ̀ wọn kọjá, wọ́n bá gba ọ̀nà ibòmíràn. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Kadeṣi, wọ́n wá sí òkè Hori ní agbègbè ilẹ̀ Edomu. Níbẹ̀ ni OLUWA ti sọ fún Mose ati Aaroni pé, “Níhìn-ín ni Aaroni yóo kú sí, kò ní dé ilẹ̀ tí mo ti ṣe ìlérí pé n óo fún àwọn ọmọ Israẹli, nítorí pé ẹ̀yin mejeeji lòdì sí àṣẹ mi ní Meriba. Nítorí náà mú Aaroni ati ọmọ rẹ̀ Eleasari wá sórí òkè Hori. Níbẹ̀ ni kí o ti bọ́ aṣọ alufaa tí ó wà lọ́rùn Aaroni, kí o gbé e wọ Eleasari. Níbẹ̀ ni Aaroni óo kú sí.” Mose ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA, gbogbo wọn sì gòkè Hori lọ níwájú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli. Mose bọ́ aṣọ alufaa tí ó wà lọ́rùn Aaroni, ó gbé e wọ Eleasari. Aaroni sì kú sí orí òkè náà, Mose ati Eleasari sì sọ̀kalẹ̀. Nígbà tí àwọn eniyan náà mọ̀ pé Aaroni ti kú, wọ́n ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ fún ọgbọ̀n ọjọ́. Nígbà tí ọba Aradi ará Kenaani tí ń gbé ìhà gúsù ní Nẹgẹbu Kenaani gbọ́ pé àwọn ọmọ Israẹli ń gba ọ̀nà Atarimu bọ̀, ó lọ bá wọn jagun, ó sì kó ninu wọn lẹ́rú. Nígbà náà ni àwọn ọmọ Israẹli bá OLUWA jẹ́jẹ̀ẹ́ pé, Bí ó bá ti àwọn lẹ́yìn tí àwọn bá ṣẹgun àwọn eniyan náà, àwọn óo pa àwọn eniyan náà run patapata. OLUWA gbọ́ ohùn àwọn ọmọ Israẹli, ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣẹgun àwọn ará Kenaani. Wọ́n run àwọn ati àwọn ìlú wọn patapata. Àwọn ọmọ Israẹli sì sọ ibẹ̀ ní Horima. Àwọn ọmọ Israẹli gbéra láti òkè Hori, wọ́n gba ọ̀nà Òkun Pupa, láti yípo lọ lẹ́yìn ilẹ̀ Edomu. Ṣugbọn sùúrù tán àwọn eniyan náà lójú ọ̀nà, wọ́n sì sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọrun ati Mose, wọ́n ní, “Kí ló dé tí ẹ fi kó wa wá láti Ijipti, pé kí á wá kú ninu aṣálẹ̀ yìí? Kò sí oúnjẹ, kò sí omi, burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ yìí ti sú wa.” OLUWA bá rán ọpọlọpọ ejò amúbíiná sí àwọn eniyan náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bù wọ́n jẹ, ọpọlọpọ ninu wọn sì kú. Wọ́n bá wá sọ́dọ̀ Mose, wọ́n ní, “A ti ṣẹ̀ nítorí tí a ti sọ̀rọ̀ òdì sí OLUWA ati sí ọ. Gbadura sí OLUWA kí ó mú ejò wọnyi kúrò lọ́dọ̀ wa.” Mose bá gbadura fún àwọn eniyan náà. OLUWA sọ fún Mose pé, “Fi idẹ rọ ejò amúbíiná kan, kí o gbé e kọ́ sórí ọ̀pá gígùn kan, ẹnikẹ́ni tí ejò bá bù jẹ, tí ó bá wo ejò idẹ náà yóo yè.” Mose bá rọ ejò idẹ kan, ó gbé e kọ́ sórí ọ̀pá gígùn kan, ẹnikẹ́ni tí ejò bá bù jẹ, tí ó bá ti wò ó, a sì yè. Àwọn ọmọ Israẹli ṣí kúrò níbẹ̀, wọ́n pa àgọ́ wọn sí Obotu. Lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Obotu wọ́n pa àgọ́ sí Òkè-Abarimu ní aṣálẹ̀ tí ó wà níwájú Moabu, ní ìhà ìlà oòrùn. Wọ́n gbéra láti ibẹ̀, wọ́n lọ pa àgọ́ sí àfonífojì Seredi. Wọ́n tún ṣí kúrò ní àfonífojì Seredi, wọ́n pa àgọ́ wọn sí òdìkejì odò Arinoni, tí ó wà ní aṣálẹ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ láti agbègbè àwọn ará Amori. Odò Arinoni jẹ́ ààlà ilẹ̀ Moabu, ó wà láàrin ilẹ̀ Moabu ati ilẹ̀ Amori. Nítorí náà ni a ṣe kọ ọ́ sinu Ìwé Ogun OLUWA pé: “Ìlú Wahebu ní agbègbè Sufa, ati àwọn àfonífojì Arinoni, ati ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àwọn àfonífojì náà tí ó lọ títí dé ìlú Ari, tí ó lọ dé ààlà Moabu.” Láti ibẹ̀, wọ́n ṣí lọ sí Beeri, níbi kànga tí ó wà níbẹ̀ ni OLUWA ti sọ fún Mose pé, “Pe àwọn eniyan náà jọ, n óo sì fún wọn ní omi.” Nígbà náà ni àwọn ọmọ Israẹli kọ orin yìí pe: “Ẹ sun omi jáde, ẹ̀yin kànga! Ẹ máa kọrin sí i! Kànga tí àwọn ọmọ aládé gbẹ́, tí àwọn olórí wà pẹlu ọ̀pá àṣẹ ọba ati ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀ wọn.” Wọ́n sì ṣí kúrò níbẹ̀ lọ sí aṣálẹ̀ Matana. Láti Matana, wọ́n ṣí lọ sí Nahalieli, láti Nahalieli wọ́n ṣí lọ sí Bamotu, láti Bamotu wọ́n ṣí lọ sí àfonífojì tí ó wà ní ilẹ̀ àwọn Moabu ní ìsàlẹ̀ òkè Pisiga tí ó kọjú sí aṣálẹ̀. Àwọn ọmọ Israẹli bá ranṣẹ sí Sihoni ọba àwọn ará Amori pé, “Jọ̀wọ́, gbà wá láàyè láti gba orí ilẹ̀ rẹ kọjá. Àwa ati àwọn ẹran ọ̀sìn wa kò ní yà kúrò ní ojú ọ̀nà wọ inú oko yín, tabi ọgbà àjàrà yín. Bẹ́ẹ̀ ni a kò ní mu omi kànga yín. Ojú ọ̀nà ọba ni a óo máa rìn títí a óo fi la ilẹ̀ rẹ kọjá.” Sihoni kò gbà kí àwọn ọmọ Israẹli gba orí ilẹ̀ rẹ̀ kọjá. Ṣugbọn ó kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n sì bá àwọn ọmọ Israẹli jagun ní Jahasi ninu aṣálẹ̀. Àwọn ọmọ Israẹli pa pupọ ninu wọn, wọ́n gba ilẹ̀ wọn láti odò Arinoni lọ dé odò Jaboku títí dé ààlà àwọn ará Amoni. Wọn kò gba ilẹ̀ àwọn ará Amoni nítorí pé wọ́n jẹ́ alágbára. Àwọn ọmọ Israẹli gba gbogbo ìlú àwọn ará Amori, Heṣiboni ati àwọn ìlú tí ó wà ní agbègbè rẹ̀, wọ́n sì ń gbé inú wọn. Heṣiboni ni olú ìlú Sihoni, ọba àwọn ará Amori. Ọba yìí ni ó bá ọba Moabu jà, ó sì gba ilẹ̀ rẹ̀ títí dé odò Arinoni. Ìdí èyí ni àwọn akọrin òwe ṣe ń kọrin pé: “Wá sí Heṣiboni! Jẹ́ kí á tẹ ìlú ńlá Sihoni dó, kí á sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀. Ní àkókò kan, láti ìlú Heṣiboni, àwọn ọmọ ogun Sihoni jáde lọ bí iná; wọ́n run ìlú Ari ní Moabu, ati àwọn oluwa ibi gíga Arinoni. Ẹ̀yin ará Moabu, ẹ gbé! Ẹ di ẹni ìparun, ẹ̀yin ọmọ oriṣa Kemoṣi! Ó ti sọ àwọn ọmọkunrin yín di ẹni tí ń sálọ fún ààbò; ó sì sọ àwọn ọmọbinrin yín di ìkógun fún Sihoni ọba àwọn ará Amori. Ṣugbọn nisinsinyii, a ti pa ìrandíran wọn run, láti Heṣiboni dé Diboni, láti Naṣimu dé Nofa lẹ́bàá Medeba.” Àwọn ọmọ Israẹli sì tẹ̀dó sí ilẹ̀ àwọn ará Amori. Mose rán eniyan lọ ṣe amí Jaseri, wọ́n sì gba àwọn ìlú agbègbè rẹ̀, wọ́n lé àwọn ará Amori tí ń gbé inú rẹ̀ kúrò. Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣí, wọ́n gba ọ̀nà Baṣani. Ogu ọba Baṣani sì bá wọn jagun ní Edirei. Ṣugbọn OLUWA sọ fún Mose pé, “Má bẹ̀rù rẹ̀, mo ti fi òun ati ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́. Kí o ṣe é bí o ti ṣe Sihoni ọba àwọn ará Amori tí ń gbé Heṣiboni.” Àwọn ọmọ Israẹli pa Ogu ati àwọn ọmọ rẹ̀ ati gbogbo eniyan rẹ̀. Wọn kò dá ẹnìkan sí, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn. Àwọn ọmọ Israẹli ṣí kúrò, wọ́n lọ pa àgọ́ wọn sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní òdìkejì Jọdani tí ó kọjú sí Jẹriko. Nígbà tí Balaki ọmọ Sipori, ọba Moabu rí gbogbo ohun tí àwọn ọmọ Israẹli ṣe sí àwọn ará Amori, ẹ̀rù wọn ba òun ati àwọn eniyan rẹ̀ lọpọlọpọ, nítorí pé wọ́n pọ̀. Jìnnìjìnnì bo gbogbo àwọn ará Moabu nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ará Moabu ranṣẹ sí àwọn olórí Midiani pé, “Àwọn eniyan wọnyi yóo run gbogbo ohun tí ó wà ní àyíká wa bí ìgbà tí mààlúù bá jẹ koríko ninu pápá.” Nítorí náà, Balaki ọmọ Sipori, ọba Moabu ranṣẹ lọ pe Balaamu ọmọ Beori ní Petori lẹ́bàá Odò Yufurate ní ilẹ̀ Amawi pé, “Àwọn eniyan kan jáde ti ilẹ̀ Ijipti wá, wọ́n pàgọ́ sórí ilẹ̀ mi, wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀ náà. Agbára wọn ju tèmi lọ, nítorí náà, wá bá mi ṣépè lé wọn, bóyá bí mo bá bá wọn jagun, n óo lè ṣẹgun wọn, kí n sì lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ mi. Mo mọ̀ dájú pé ibukun ni fún ẹni tí o bá súre fún; ẹni tí o bá ṣépè fún, olúwarẹ̀ gbé!” Àwọn àgbààgbà Moabu ati Midiani mú owó iṣẹ́ aláfọ̀ṣẹ lọ́wọ́, wọ́n tọ Balaamu wá, wọ́n sì jíṣẹ́ Balaki fún un. Balaamu sọ fún wọn pé, “Ẹ sùn níbí ní alẹ́ yìí, bí ó bá di ọ̀la, n óo sọ ohun tí OLUWA bá sọ fún mi fun yín.” Àwọn àgbààgbà náà sì dúró lọ́dọ̀ Balaamu. Ọlọrun tọ Balaamu wá, ó bi í pé, “Àwọn ọkunrin wo ni wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ yìí?” Balaamu dáhùn pé, “Balaki ọba àwọn ará Moabu ni ó rán wọn sí mi pé, àwọn eniyan kan, tí wọ́n wá láti Ijipti, tẹ̀dó sórí gbogbo ilẹ̀ òun. Ó fẹ́ kí n wá bá òun ṣépè lé wọn, kí ó lè bá wọn jà, kí ó sì lè lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ rẹ̀.” Ọlọrun sọ fún Balaamu pé, “Má bá wọn lọ, má sì ṣépè lé àwọn eniyan náà nítorí ẹni ibukun ni wọ́n.” Nígbà tí Balaamu jí ní òwúrọ̀, ó sọ fún àwọn oníṣẹ́ Balaki pé, “Ẹ máa lọ sí ilẹ̀ yín nítorí OLUWA ti sọ pé n kò gbọdọ̀ ba yín lọ.” Nígbà náà ni wọ́n pada lọ sọ́dọ̀ Balaki, wọn sì sọ fún un wí pé Balaamu kọ̀, kò bá àwọn wá. Balaki tún rán àwọn àgbààgbà mìíràn tí wọ́n pọ̀, tí wọ́n sì ṣe pataki ju àwọn ti iṣaaju lọ sí ọ̀dọ̀ Balaamu. Wọ́n jíṣẹ́ fún un pé Balaki ní, “Mo bẹ̀ ọ́, má jẹ́ kí ohunkohun dí ọ lọ́wọ́ láti wá sọ́dọ̀ mi. N óo sọ ọ́ di eniyan pataki, ohunkohun tí o bá sọ, n óo ṣe é. Jọ̀wọ́ wá bá mi ṣépè lé àwọn eniyan wọnyi.” Balaamu dá àwọn oníṣẹ́ Balaki lóhùn pé, “Balaki ìbáà fún mi ní ààfin rẹ̀, kí ààfin náà sì kún fún fadaka ati wúrà, n kò ní lòdì sí àṣẹ OLUWA Ọlọrun mi, ninu nǹkan kékeré tabi nǹkan ńlá. Ṣugbọn ẹ sùn níbí ní alẹ́ yìí, kí n lè mọ ohun tí OLUWA yóo tún bá mi sọ.” Ní òru ọjọ́ náà, Ọlọrun tọ Balaamu wá, ó ní, “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ọkunrin wọnyi wá bẹ̀ ọ́ pé kí o bá wọn lọ, máa bá wọn lọ, ṣugbọn ohun tí mo bá sọ fún ọ ni o gbọdọ̀ ṣe.” Ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, Balaamu di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó sì bá àwọn àgbààgbà Moabu lọ. OLUWA bínú sí Balaamu nítorí pé ó bá wọn lọ. Bí ó ti ń lọ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ pẹlu àwọn iranṣẹ rẹ̀ meji, angẹli OLUWA dúró ní ojú ọ̀nà rẹ̀ ó dínà fún un. Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà rí angẹli tí ó dúró ní ọ̀nà pẹlu idà ní ọwọ́ rẹ̀, ó yà kúrò ní ojú ọ̀nà sinu igbó. Balaamu lu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà láti darí rẹ̀ sójú ọ̀nà. Angẹli náà tún dúró ní ọ̀nà tóóró láàrin ọgbà àjàrà meji, ògiri sì wà ní ìhà mejeeji. Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà rí i, ó fún ara rẹ̀ mọ́ ògiri, ẹsẹ̀ Balaamu sì fún mọ́ ògiri pẹlu, Balaamu bá tún lù ú. Lẹ́ẹ̀kan sí i, angẹli náà lọ siwaju, ó dúró ní ọ̀nà tóóró kan níbi tí kò sí ààyè rárá láti yà sí. Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà rí angẹli náà, ó wó lulẹ̀ lábẹ́ Balaamu. Inú bí Balaamu gidigidi, ó sì fi ọ̀pá rẹ̀ na kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà. Nígbà náà ni OLUWA la kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà lóhùn ó sì sọ̀rọ̀ bí eniyan, ó sì sọ fún Balaamu pé, “Kí ni mo fi ṣe ọ́ tí o fi lù mí nígbà mẹta?” Balaamu dáhùn pé, “Nítorí tí ò ń fi mí ṣẹ̀sín, bí ó bá jẹ́ pé idà wà lọ́wọ́ mi ni, ǹ bá ti pa ọ́.” Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà dáhùn pé, “Ṣebí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ ni mí, tí o sì ti ń gùn mí láti iye ọjọ́ yìí títí di òní? Ǹjẹ́ mo hu irú ìwà báyìí sí ọ rí?” Balaamu dáhùn pé, “Rárá o.” Nígbà náà ni OLUWA la Balaamu lójú láti rí angẹli tí ó dúró lójú ọ̀nà pẹlu idà lọ́wọ́ rẹ̀, Balaamu sì dojúbolẹ̀. Angẹli náà bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ló dé tí o fi lu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ nígbà mẹta? Mo wá láti dínà fún ọ nítorí pé kò yẹ kí o rin ìrìn àjò yìí. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ rí mi, ó sì yà fún mi nígbà mẹta, bí bẹ́ẹ̀ bá kọ́, ǹ bá ti pa ọ́, ǹ bá sì dá òun sí.” Balaamu dá angẹli náà lóhùn pé, “Mo ti dẹ́ṣẹ̀, n kò sì mọ̀ pé o dúró lójú ọ̀nà láti dínà fún mi. Ó dára, bí o kò bá fẹ́ kí n lọ, n óo pada.” Angẹli OLUWA sì dáhùn pé, “Máa bá àwọn ọkunrin náà lọ, ṣugbọn ohun tí mo bá sọ fún ọ ni kí o sọ.” Balaamu sì bá wọn lọ. Nígbà tí Balaki gbọ́ pé Balaamu ń bọ̀, ó jáde lọ pàdé rẹ̀ ní ìlú Moabu tí ó wà létí odò Arinoni ní ààlà ilẹ̀ Moabu. Balaki wí fún un pé, “Kí ló dé tí o kò fi wá nígbà tí mo ranṣẹ sí ọ lákọ̀ọ́kọ́? Ṣé o rò pé n kò lè sọ ọ́ di ẹni pataki ni?” Balaamu dáhùn pé, “Wíwá tí mo wá yìí, èmi kò ní agbára láti sọ ohunkohun bíkòṣe ohun tí OLUWA bá sọ fún mi.” Balaamu bá Balaki lọ sí ìlú Kiriati-husotu. Níbẹ̀ ni Balaki ti fi akọ mààlúù ati aguntan ṣe ìrúbọ, ó sì fún Balaamu ati àwọn àgbààgbà tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ninu ẹran náà. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, Balaki mú Balaamu lọ sí ibi gegele Bamotu Baali níbi tí ó ti lè rí apá kan àwọn ọmọ Israẹli. Balaamu sọ fún Balaki pé, “Tẹ́ pẹpẹ meje sí ibí yìí fún mi kí o sì pèsè akọ mààlúù meje ati àgbò meje.” Balaki ṣe gẹ́gẹ́ bí Balaamu ti wí, àwọn mejeeji sì fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan. Balaamu bá sọ fún Balaki pé, “Dúró níhìn-ín, lẹ́bàá ẹbọ sísun rẹ, n óo máa lọ bóyá OLUWA yóo wá pàdé mi. Ohunkohun tí ó bá fihàn mí, n óo sọ fún ọ.” Ó bá lọ sórí òkè kan. Ọlọrun lọ bá a níbẹ̀, Balaamu sì sọ fún Ọlọrun pé, “Mo ti tẹ́ pẹpẹ meje, mo sì ti fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.” OLUWA bá rán Balaamu pada sí Balaki, ó sọ ohun tí yóo sọ fún un. Nígbà tí ó pada dé, ó bá Balaki ati àwọn àgbààgbà Moabu, wọ́n dúró ti àwọn ẹbọ sísun náà. Balaamu bá bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, ó ní: “Láti Aramu, Balaki mú mi wá, ọba Moabu mú mi wá láti àwọn òkè ìlà oòrùn. Ó sọ pé, ‘Wá ba mi ṣépè lé Jakọbu, kí o sì fi Israẹli ré.’ Ẹni tí OLUWA kò gbé ṣépè, báwo ni mo ṣe lè ṣépè lé e? Ẹni tí OLUWA kò ṣépè lé, báwo ni mo ṣe lè gbé e ṣépè? Mo rí wọn láti òkè gíga, mò ń wò wọ́n láti orí àwọn òkè. Wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè tí ń dá gbé; wọn kò da ara wọn pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè yòókù. Ta ló lè ka àwọn ọmọ Jakọbu tí ó pọ̀ bí iyanrìn? Tabi kí ó ka idamẹrin àwọn ọmọ Israẹli? Jẹ́ kí n kú ikú olódodo, kí ìgbẹ̀yìn mi sì dàbí tirẹ̀.” Nígbà náà ni Balaki sọ fún Balaamu pé, “Kí ni ò ń ṣe sí mi yìí? Mo mú ọ wá láti ṣépè lé àwọn ọ̀tá mi, ṣugbọn ò ń súre fún wọn.” Ó sì dáhùn pé, “Ohun tí OLUWA bá sọ fún mi ni mo gbọdọ̀ sọ.” Balaki sọ fún Balaamu pé, “Jẹ́ kí á lọ sí ibòmíràn tí o ti lè rí wọn. Apákan wọn ni o óo rí, o kò ní rí gbogbo wọn, níbẹ̀ ni o óo ti bá mi ṣépè lé wọn.” Ó bá mú un lọ sórí òkè Pisiga ní pápá Sofimu. Ó tún tẹ́ pẹpẹ meje, ó sì fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan. Balaamu sọ fún Balaki pé, “Dúró ti ẹbọ sísun rẹ, n óo lọ pàdé OLUWA lọ́hùn-ún.” OLUWA rán Balaamu pada sí Balaki pẹlu ohun tí yóo sọ. Nígbà tí ó pada dé ó bá Balaki ati àwọn àgbààgbà Moabu, wọ́n dúró ti ẹbọ sísun náà, Balaki sì bèèrè ohun tí OLUWA sọ lọ́wọ́ rẹ̀. Balaamu bá bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, ó ní: “Balaki, dìde, wá gbọ́, fetí sí mi, ọmọ Sipori; Ọlọrun kò jọ eniyan tí máa ń purọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe eniyan tí máa ń yí ọkàn pada. Ohun tí ó bá ti sọ ni yóo ṣe, bí ó bá sì sọ̀rọ̀ yóo rí bẹ́ẹ̀. OLUWA ti sọ fún mi pé kí n bukun wọn, Ọlọrun pàápàá ti bukun wọn, èmi kò lè mú ibukun náà kúrò. Kò rí ìparun ninu Jakọbu, bẹ́ẹ̀ ni kò rí ìpọ́njú níwájú Israẹli. OLUWA Ọlọrun wọn wà pẹlu wọn, Òun sì ni ọba wọn. OLUWA mú wọn jáde láti Ijipti wá, Ó sì ń jà fún wọn bí àgbáǹréré. Kò sí òògùn kan tí ó lè ran Jakọbu, bẹ́ẹ̀ ni àfọ̀ṣẹ kan kò lè ran Israẹli. Wò ó! Àwọn eniyan yóo máa wí nípa Israẹli pé, ‘Wo ohun tí Ọlọrun ṣe!’ Wo orílẹ̀-èdè Israẹli! Ó dìde dúró bí abo kinniun, ó sì gbé ara rẹ̀ sókè bíi kinniun. Kò ní sinmi títí yóo fi jẹ ẹran tí ó pa tán, tí yóo sì fi mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tán.” Balaki sì sọ fún Balaamu pé, “Níwọ̀n ìgbà tí o ti kọ̀, tí o kò ṣépè lé wọ́n, má súre fún wọn.” Balaamu dá a lóhùn pé, “Ǹjẹ́ n kò tí sọ fún ọ pé ohun tí OLUWA bá sọ fún mi ni mo gbọdọ̀ sọ?” Balaki sọ fún Balaamu pé, “N óo mú ọ lọ sí ibòmíràn bóyá Ọlọrun yóo gbà pé kí o bá mi ṣépè lé àwọn eniyan náà níbẹ̀.” Ó bá mú Balaamu lọ sórí òkè Peori tí ó kọjú sí aṣálẹ̀. Balaamu sọ fún Balaki pé, “Kọ́ pẹpẹ ìrúbọ meje kí o sì mú akọ mààlúù meje ati àgbò meje wá.” Balaki ṣe ohun tí Balaamu sọ, ó sì fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan. Nígbà tí Balaamu rí i pé OLUWA ń súre fún àwọn ọmọ Israẹli, kò lọ bíi ti iṣaaju láti bá OLUWA pàdé. Ṣugbọn ó kọjú sí aṣálẹ̀, ó sì rí i bí àwọn ọmọ Israẹli ti pa àgọ́ wọn, olukuluku ẹ̀yà ni ààyè tirẹ̀. Ẹ̀mí Ọlọrun sì bà lé e, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, ó ní, “Ọ̀rọ̀ Balaamu ọmọ Beori nìyí, ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ríran dájúdájú; ìran ẹni tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, mo sì lajú sílẹ̀ kedere rí ìran láti ọ̀dọ̀ Olodumare. Nítòótọ́ ó ṣubú, ṣugbọn ojú rẹ̀ wà ní ṣíṣí sílẹ̀. Báwo ni àgọ́ rẹ ti dára tó ìwọ Jakọbu, ati ibùdó rẹ ìwọ Israẹli! Ó dàbí àfonífojì tí ó tẹ́ lọ bẹẹrẹ, bí ọgbà tí ó wà lẹ́bàá odò. Ó dàbí àwọn igi aloe tí OLUWA gbìn, ati bí igi kedari tí ó wà lẹ́bàá odò. Òjò yóo rọ̀ fún Israẹli ní àkókò rẹ̀, omi yóo jáde láti inú agbè rẹ̀; àwọn ohun ọ̀gbìn rẹ̀ yóo sì rí omi mu. Ọba wọn yóo lókìkí ju Agagi lọ, ìjọba rẹ̀ ni a óo sì gbéga. Ọlọrun kó wọn ti Ijipti wá, ó jà fún wọn gẹ́gẹ́ bí àgbáǹréré. Wọn yóo pa àwọn ọ̀tá wọn run, wọn óo wó egungun wọn, wọn óo sì fi ọfà pa wọ́n. Ó dùbúlẹ̀, ó ba bíi kinniun, bí abo kinniun tí ó sùn, ta ló lè jí i dìde? Ibukun ni fún ẹni tí ó bá súre fún Israẹli, ẹni tí ó bá sì gbé Israẹli ṣépè, olúwarẹ̀ gbé!” Balaki bá bínú sí Balaamu gidigidi, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi ọwọ́ lu ọwọ́. Ó sì sọ fún Balaamu pé: “Mo pè ọ́ pé kí o wá gbé àwọn ọ̀tá mi ṣépè, ṣugbọn dípò kí o gbé wọ́n ṣépè, o súre fún wọn ní ìgbà mẹta! Nítorí náà máa lọ sí ilé rẹ. Mo ti pinnu láti sọ ọ́ di eniyan pataki tẹ́lẹ̀ ni, ṣugbọn OLUWA ti dí ọ lọ́nà.” Balaamu bá dáhùn pé: “Ṣebí mo ti sọ fún àwọn oníṣẹ́ tí o rán wá pé, bí o tilẹ̀ fún mi ní ààfin rẹ, tí ó sì kún fún fadaka ati wúrà, sibẹsibẹ, n kò ní agbára láti ṣe ohunkohun ju ohun tí OLUWA bá sọ lọ. N kò lè dá ṣe rere tabi burúkú ní agbára mi, ohun tí OLUWA bá sọ ni n óo sọ.” Balaamu tún sọ fún Balaki pé, “Èmi ń lọ sí ilé mi, ṣugbọn jẹ́ kí n kìlọ̀ fún ọ nípa ohun tí àwọn eniyan wọnyi yóo ṣe sí àwọn eniyan rẹ ní ẹ̀yìn ọ̀la.” Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, pé, “Ọ̀rọ̀ Balaamu ọmọ Beori nìyí, ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ríran dájúdájú. Ìran ẹni tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun, tí ó ní ìmọ̀ ẹni tí ó ga jùlọ, tí ó sì ń rí ìran láti ọ̀dọ̀ Olodumare. Nítòótọ́ ó ṣubú, ṣugbọn ojú rẹ̀ kò wà ní dídì. Mo wo ọjọ́ iwájú rẹ, mo sì rí ẹ̀yìn ọ̀la rẹ. Ìràwọ̀ kan yóo jáde wá láàrin àwọn ọmọ Jakọbu, ọ̀pá àṣẹ yóo ti ààrin àwọn ọmọ Israẹli jáde wá; yóo run àwọn àgbààgbà Moabu, yóo sì wó àwọn ará Seti palẹ̀. Yóo ṣẹgun àwọn ọ̀tá rẹ̀ ní Edomu, yóo sì gba ilẹ̀ wọn. Yóo ṣẹgun àwọn ará Seiri tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá wọn, yóo sì gba ilẹ̀ wọn. Israẹli yóo sì máa pọ̀ sí i ní agbára. Láti inú ìdílé Jakọbu ni àṣẹ ọba yóo ti jáde wá, yóo sì pa àwọn tí ó kù ninu ìlú náà run.” Nígbà tí ó wo Amaleki, ó fi òwe sọ̀rọ̀ nípa wọn báyìí pé: “Amaleki ni orílẹ̀-èdè tí ó lágbára jùlọ, Ṣugbọn yóo ṣègbé níkẹyìn.” Nígbà tí ó wo àwọn ará Keni, ó fi òwe sọ̀rọ̀ nípa wọn báyìí pé: “Ibi ìpamọ́ tí ẹ̀ ń gbé dàbí ìtẹ́ tí ó wà lórí àpáta gíga. Ṣugbọn ẹ̀yin ará Keni yóo di ẹni ìparun, àwọn ará Aṣuri yóo ko yín lẹ́rú.” Balaamu tún fi òwe sọ ọ̀rọ̀ wọnyi: “Ta ni yóo là nígbà tí Ọlọrun bá ṣe nǹkan wọnyi? Àwọn ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n kún fún ọmọ ogun yóo wá láti Kitimu, wọn yóo borí àwọn ará Aṣuri ati Eberi, ṣugbọn Kitimu pàápàá yóo ṣègbé.” Balaamu bá dìde, ó pada sí ilé rẹ̀; Balaki náà bá pada sí ilé rẹ̀. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli pàgọ́ sí àfonífojì Ṣitimu, àwọn ọkunrin wọn ń bá àwọn ọmọbinrin Moabu tí wọ́n wà níbẹ̀ ṣe àgbèrè. Àwọn obinrin wọnyi a sì máa pè wọ́n lọ síbi àsè ìbọ̀rìṣà. Wọn a máa jẹ oúnjẹ wọn, wọn a sì ma bá wọn bọ oriṣa wọn. Báyìí ni àwọn ọmọ Israẹli ṣe da ara wọn pọ̀ mọ́ oriṣa Baali tí ó wà ní Peori, ibinu OLUWA sì ru sí wọn. OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Mú gbogbo àwọn olórí Israẹli, kí o so wọ́n kọ́ sórí igi ninu oòrùn títí tí wọn óo fi kú níwájú OLUWA. Nígbà náà ni n kò tó ni bínú sí àwọn eniyan náà mọ́.” Mose sì wí fún àwọn onídàájọ́ Israẹli pé, “Olukuluku yín gbọdọ̀ pa àwọn eniyan rẹ̀ tí ó lọ sin oriṣa Baali tí ó wà ní Peori.” Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Israẹli mú ọmọbinrin Midiani wọlé lójú Mose ati gbogbo àwọn eniyan, níbi tí wọ́n ti ń sọkún lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ níwájú OLUWA. Nígbà tí Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni, alufaa, rí i, ó dìde láàrin àwọn eniyan, ó sì mú ọ̀kọ̀ kan, ó tọ ọkunrin náà lọ ninu àgọ́ rẹ̀, ó sì fi ọ̀kọ̀ náà gún òun ati obinrin náà ní àgúnyọ. Àjàkálẹ̀ àrùn sì dúró láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn tí wọ́n kú ninu àjàkálẹ̀ àrùn náà jẹ́ ẹgbaa mejila (24,000). OLUWA sọ fún Mose pé, “N kò ní bínú sí Israẹli mọ nítorí ohun tí Finehasi ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni, alufaa, ṣe. Ó kọ̀ láti gba ìbọ̀rìṣà láàyè, nítorí náà ni n kò ṣe ní fi ibinu pa àwọn ọmọ Israẹli run. Nítorí náà, sọ fún un pé mo bá a dá majẹmu alaafia. Majẹmu náà ni pé mo ti yan òun ati arọmọdọmọ rẹ̀ láti máa ṣe alufaa ní Israẹli títí lae nítorí pé ó ní ìtara fún Ọlọrun rẹ̀, ó sì ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan Israẹli.” Orúkọ ọmọ Israẹli tí ó pa pẹlu ọmọbinrin Midiani ni Simiri, ọmọ Salu, olórí ilé kan ninu ẹ̀yà Simeoni. Orúkọ ọmọbinrin Midiani náà ni Kosibi, ọmọ Suri, baálé ilé kan ní ilẹ̀ Midiani. OLUWA sọ fún Mose pé, “Kọlu àwọn ará Midiani, kí o sì pa wọ́n run nítorí ibi tí wọ́n ṣe, ati títàn tí wọ́n tàn yín ní Peori, ati nítorí ọ̀rọ̀ Kosibi, ọmọ baálé kan ní ilẹ̀ Midiani, arabinrin wọn, tí a pa nígbà àjàkálẹ̀ àrùn ti Peori.” Lẹ́yìn àjàkálẹ̀ àrùn náà, OLUWA sọ fún Mose ati Eleasari alufaa ọmọ Aaroni pé, “Ẹ ka iye àwọn ọmọ Israẹli, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé.” Mose ati Eleasari alufaa sì pe àwọn eniyan náà jọ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, lẹ́bàá odò Jọdani, létí Jẹriko, wọ́n sọ fún wọn pé, “Ẹ ka iye àwọn eniyan náà láti ẹni ogún ọdún lọ sókè,” gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n jáde láti ilẹ̀ Ijipti nìwọ̀nyí: Reubẹni ni àkọ́bí Israẹli. Àwọn ọmọ Reubẹni ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Hanoku, ìdílé Palu, ìdílé Hesironi, ìdílé Karimi. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Reubẹni jẹ́ ẹgbaa mọkanlelogun ó lé ẹgbẹsan ó dín aadọrin (43,730). Palu bí Eliabu, Eliabu bí Nemueli, Datani ati Abiramu. Datani ati Abiramu yìí ni wọ́n jẹ́ olókìkí eniyan láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ni wọ́n bá Mose ati Aaroni ṣe gbolohun asọ̀ nígbà tí Kora dìtẹ̀, tí wọ́n tako OLUWA. Nígbà náà ni ilẹ̀ lanu, tí ó gbé wọn mì pẹlu Kora, wọ́n sì kú, òun ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Nígbà náà ni iná jó àwọn aadọta leerugba (250) ọkunrin tí wọn tẹ̀lé Kora, wọ́n sì di ohun ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli. Ṣugbọn àwọn ọmọ Kora kò kú. Àwọn ọmọ Simeoni ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Nemueli, ìdílé Jamini, ati ìdílé Jakini; ìdílé Sera ati ti Ṣaulu. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Simeoni jẹ́ ẹgbaa mọkanla ó lé igba (22,200). Àwọn ọmọ Gadi ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Sefoni, ìdílé Hagi, ati ìdílé Ṣuni; ìdílé Osini, ati ìdílé Eri; ìdílé Arodu ati ìdílé Areli. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Gadi jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (40,500). Àwọn ọmọ Juda ni Eri ati Onani. Eri ati Onani kú ní ilẹ̀ Kenaani. Àwọn ọmọ Juda ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Ṣela, ìdílé Peresi, ati ìdílé Sera. Àwọn ọmọ Peresi nìwọ̀nyí: ìdílé Hesironi ati ìdílé Hamuli. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Juda jẹ́ ẹgbaa mejidinlogoji ó lé ẹẹdẹgbẹta (76,500). Àwọn ọmọ Isakari ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Tola, ìdílé Pua; ìdílé Jaṣubu ati ìdílé Ṣimironi. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Isakari jẹ́ ẹgbaa mejilelọgbọn ó lé ọọdunrun (64,300). Àwọn ọmọ Sebuluni ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Seredi, ìdílé Eloni ati ìdílé Jaleeli. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Sebuluni jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹta ó lé ẹẹdẹgbẹta (60,500). Àwọn ọmọ Josẹfu ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: Manase ati Efuraimu. Àwọn ọmọ Manase ni: ìdílé Makiri, Makiri bí Gileadi. Àwọn ọmọ Gileadi nìwọ̀nyí: ìdílé Ieseri, ìdílé Heleki; ìdílé Asirieli, ìdílé Ṣekemu; ìdílé Ṣemida, ìdílé Heferi. Selofehadi ọmọ Heferi kò bí ọmọkunrin kankan, àfi ọmọbinrin. Orúkọ àwọn ọmọbinrin Selofehadi ni Mahila, Noa, Hogila, Milika ati Tirisa. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ìdílé Manase jẹ́ ẹgbaa mẹrindinlọgbọn ó lé ẹẹdẹgbẹrin (52,700). Àwọn ọmọ Efuraimu ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Ṣutela, ìdílé Bekeri ati ìdílé Tahani. Àwọn ọmọ Ṣutela nìwọ̀nyí, ìdílé Erani. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Efuraimu jẹ́ ẹgbaa mẹrindinlogun ó lé ẹẹdẹgbẹta (32,500). Àwọn ni ọmọ Josẹfu ní ìdílé-ìdílé. Àwọn ọmọ Bẹnjamini ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Bela, ìdílé Aṣibeli, ìdílé Ahiramu; ìdílé Ṣefufamu ati ìdílé Hufamu. Àwọn ọmọ Bela nìwọ̀nyí: ìdílé Aridi ati ìdílé Naamani. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Bẹnjamini jẹ́ ẹgbaa mejilelogun ó lé ẹgbẹjọ (45,600). Àwọn ọmọ Dani ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Ṣuhamu. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Dani jẹ́ ẹgbaa mejilelọgbọn ó lé irinwo (64,400). Àwọn ọmọ Aṣeri ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Imina, ìdílé Iṣifi ati ìdílé Beria. Àwọn ọmọ Beria ni: ìdílé Heberi ati ìdílé Malikieli. Orúkọ ọmọ Aṣeri obinrin sì ni Sera. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Aṣeri jẹ́ ẹgbaa mẹrindinlọgbọn ó lé egbeje (53,400). Àwọn ọmọ Nafutali ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Jahiseeli, ìdílé Guni, ìdílé Jeseri ati ìdílé Ṣilemu. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Nafutali jẹ́ ẹgbaa mejilelogun ó lé egbeje (45,400). Gbogbo wọn ní àpapọ̀ jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé ẹgbẹsan ó dín aadọrin (601,730). OLUWA sọ fún Mose pé, “Àwọn wọnyi ni kí o pín ilẹ̀ náà fún gẹ́gẹ́ bí iye wọn. Fún àwọn tí ó pọ̀ ní ilẹ̀ pupọ ati àwọn tí ó kéré ní ilẹ̀ kéékèèké. Bí iye eniyan tí ó wà ninu ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan bá ti pọ̀ sí ni kí ẹ fi pín ilẹ̀ náà fún wọn. Gègé ni kí ẹ ṣẹ́, kí ẹ fi pín ilẹ̀ náà fún olukuluku ẹ̀yà gẹ́gẹ́ bí iye wọn. Gègé ni kí ẹ ṣẹ́ kí ẹ pín ilẹ̀ náà láàrin àwọn ẹ̀yà tí ó pọ̀ ati àwọn ẹ̀yà kéékèèké.” Àwọn ọmọ Lefi ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Geriṣoni, ìdílé Kohati ati ìdílé Merari, Àwọn ìdílé tí ó wà ninu ẹ̀yà Lefi nìwọ̀nyí: ìdílé Libini, ìdílé Heburoni, ìdílé Mahili, ìdílé Muṣi ati ìdílé Kora. Kohati ni baba Amramu. Orúkọ aya Amramu ni Jokebedi, ọmọbinrin Lefi tí ìyá rẹ̀ bí fún Lefi ní Ijipti. Ó bí Aaroni ati Mose ati Miriamu, arabinrin wọn fún Amramu. Àwọn ọmọ Aaroni ni Nadabu, Abihu, Eleasari ati Itamari. Nadabu ati Abihu kú nígbà tí wọ́n rúbọ sí OLUWA ninu Àgọ́ Àjọ pẹlu iná tí kò mọ́. Gbogbo àwọn ọmọkunrin tí a kà ninu ẹ̀yà Lefi láti ẹni oṣù kan sókè jẹ́ ẹgbaa mọkanla ó lé ẹgbẹrun (23,000). Wọn kò kà wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Israẹli nítorí pé wọn kò ní ilẹ̀ ìní ní Israẹli. Gbogbo àwọn tí Mose ati Eleasari kà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá Jọdani létí Jẹriko nìwọ̀nyí. Ṣugbọn kò sí ẹnìkan tí ó tíì dáyé ninu wọn nígbà tí Mose ati Aaroni alufaa, ka àwọn ọmọ Israẹli ní aṣálẹ̀ Sinai. Nítorí pé OLUWA ti sọ pé gbogbo àwọn ti ìgbà náà ni yóo kú ninu aṣálẹ̀. Kalebu ọmọ Jefune ati Joṣua ọmọ Nuni nìkan ni ó kù lára wọn. Nígbà náà ni Mahila, Noa, Hogila, Milika ati Tirisa, àwọn ọmọbinrin Selofehadi, ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manase, ti ìdílé Manase, ọmọ Josẹfu, lọ fi ẹjọ́ sun Mose ati Eleasari alufaa ati àwọn olórí àwọn ọmọ Israẹli níwájú Àgọ́ Àjọ pé, “Baba wa kú sinu aṣálẹ̀ láìní ọmọkunrin kankan. Kò sí lára àwọn ẹgbẹ́ Kora tí ó ṣọ̀tẹ̀ sí OLÚWA, ṣugbọn ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀ ni. Kí ló dé tí orúkọ baba wa yóo fi parẹ́ kúrò ninu ìdílé rẹ̀ nítorí pé kò ní ọmọkunrin? Nítorí náà, ẹ fún wa ní ilẹ̀ ìní láàrin àwọn eniyan baba wa.” Mose bá bá OLUWA sọ̀rọ̀ nípa wọn, OLUWA sì sọ fún un pé, “Ohun tí àwọn ọmọbinrin Selofehadi bèèrè tọ́, fún wọn ní ilẹ̀ ìní baba wọn láàrin àwọn eniyan baba wọn. Sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé nígbà tí ẹnìkan bá kú láìní ọmọkunrin, àwọn ọmọbinrin rẹ̀ yóo jogún ilẹ̀ ìní rẹ̀. Bí kò bá sì ní ọmọbinrin, ilẹ̀ ìní rẹ̀ yóo jẹ́ ti àwọn arakunrin rẹ̀. Bí kò bá ní arakunrin, kí ẹ fi ilẹ̀ ìní rẹ̀ fún àwọn arakunrin baba rẹ̀. Bí baba rẹ̀ kò bá ní arakunrin, ẹ fi ilẹ̀ ìní rẹ̀ fún ìbátan rẹ̀ tí ó bá súnmọ́ ọn jùlọ ninu ìdílé rẹ̀. Ìbátan rẹ̀ yìí ni yóo jogún rẹ̀. Èyí yóo máa jẹ́ ìlànà fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.” OLUWA sọ fún Mose pé, “Gun orí òkè Abarimu yìí lọ, kí o sì wo ilẹ̀ tí n óo fún àwọn ọmọ Israẹli. Lẹ́yìn náà tí o bá ti wò ó tán, ìwọ náà yóo kú gẹ́gẹ́ bíi Aaroni arakunrin rẹ, nítorí o ṣàìgbọràn sí àṣẹ mi ninu aṣálẹ̀ Sini. Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ń kùn sí mi ní Meriba, ẹ kọ̀ láti fi títóbi agbára mi hàn níwájú àwọn eniyan náà.” (Meriba ni wọ́n ń pe àwọn omi tí ó wà ní Kadeṣi ní aṣálẹ̀ Sini). Mose bá gbadura báyìí pé, “OLUWA Ọlọrun, ìwọ ni orísun ìyè gbogbo nǹkan alààyè. Èmi bẹ̀ ọ́, yan ẹnìkan tí yóo máa ṣáájú àwọn eniyan wọnyi: ẹni tí ó lè máa ṣáájú wọn lójú ogun, kí àwọn eniyan rẹ má baà wà bí aguntan tí kò ní olùṣọ́.” OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Mú Joṣua ọmọ Nuni, ẹni tí Ẹ̀mí èmi OLUWA wà ninu rẹ̀, gbé ọwọ́ rẹ lé e lórí, kí o mú un wá siwaju Eleasari alufaa ati gbogbo àwọn eniyan, kí o sì fún un ní àṣẹ lójú wọn. Fún un ninu iṣẹ́ rẹ, kí àwọn ọmọ Israẹli lè tẹríba fún un. Yóo máa gba ìmọ̀ràn lọ́wọ́ Eleasari alufaa. Eleasari yóo sì máa lo Urimu ati Tumimu láti mọ ohun tí mo fẹ́. Ìtọ́ni Urimu ati Tumimu ni Eleasari yóo fi máa darí Joṣua ninu ohun gbogbo tí àwọn ọmọ Israẹli bá fẹ́ ṣe.” Mose ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún un. Ó mú Joṣua wá siwaju Eleasari alufaa ati gbogbo àwọn eniyan, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, ó sì fún un ní àṣẹ. OLUWA sọ fún Mose pé kí ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọn máa mú ọrẹ wá fún ohun ìrúbọ sí òun OLUWA ní àkókò rẹ̀, ati àwọn nǹkan tí wọn yóo máa fi rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn. “Ọrẹ tí wọn óo máa mú wá fún ẹbọ sísun tí ẹ óo máa rú sí OLUWA nìwọ̀nyí: ọ̀dọ́ aguntan meji ọlọ́dún kan tí kò ní àbààwọ́n fún ẹbọ sísun ojoojumọ: Ọ̀dọ́ aguntan kan fún ẹbọ àárọ̀ ati ọ̀dọ́ aguntan kan fún ẹbọ àṣáálẹ́, pẹlu ìdámẹ́wàá ìyẹ̀fun òṣùnwọ̀n efa tí a fi idamẹrin òṣùnwọ̀n hini òróró tí a gún pọ̀. Èyí ni ẹbọ sísun ojoojumọ tí a ti fi ìlànà rẹ̀ lélẹ̀ ní òkè Sinai gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA. Ẹbọ ohun mímu rẹ̀ yóo máa jẹ́ idamẹrin òṣùnwọ̀n hini fún ọ̀dọ́ aguntan kan. O óo sì ta ọtí líle náà sílẹ̀ lẹ́bàá pẹpẹ ìrúbọ bí ẹbọ sí OLUWA. Ní ìrọ̀lẹ́, kí o fi ọ̀dọ́ aguntan keji rúbọ bíi ti ẹbọ ohun jíjẹ òwúrọ̀ pẹlu ẹbọ ohun mímu rẹ̀. Èyí yóo máa jẹ́ ẹbọ sísun, olóòórùn dídùn sí OLUWA. “Ní ọjọ́ ìsinmi, ẹ fi ọ̀dọ́ aguntan meji ọlọ́dún kan tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ pẹlu idamẹrin ìyẹ̀fun òṣùnwọ̀n efa tí a fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ pẹlu ẹbọ ohun mímu. Ẹ óo máa rú ẹbọ sísun yìí ní gbogbo ọjọ́ ìsinmi pẹlu ẹbọ ojoojumọ ati ẹbọ ohun mímu. “Ẹ óo máa rú ẹbọ sísun sí OLUWA ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù. Àwọn nǹkan tí ẹ óo máa fi rúbọ ni: ọ̀dọ́ akọ mààlúù meji ati àgbò kan ati ọ̀dọ́ àgbò meje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí kò ní àbààwọ́n. Fún ẹbọ ohun jíjẹ, ẹ lo ìdámẹ́wàá mẹta ìyẹ̀fun òṣùnwọ̀n efa, tí a fi òróró pò fún akọ mààlúù kan ati idamẹrin ìyẹ̀fun òṣùnwọ̀n efa tí a fi òróró pò fún àgbò kan. Ati ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò fún ọ̀dọ́ aguntan kan. Èyí jẹ́ ẹbọ sísun olóòórùn dídùn fún OLUWA. Kí ẹbọ ohun mímu jẹ́ ààbọ̀ òṣùnwọ̀n hini ọtí waini fún akọ mààlúù kan, ìdámẹ́ta òṣùnwọ̀n hini ọtí waini fún àgbò kan ati idamẹrin òṣùnwọ̀n hini ọtí waini fún ọ̀dọ́ aguntan kan. Èyí ni ìlànà ẹbọ sísun ti ìbẹ̀rẹ̀ oṣù. Yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ yìí, ẹ óo tún fi òbúkọ kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ sí OLUWA. “Ọjọ́ kẹrinla oṣù kinni ni Àjọ̀dún Ìrékọjá OLUWA. Ọjọ́ kẹẹdogun oṣù náà ni ọjọ́ àjọ̀dún, ẹ óo máa jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà fún ọjọ́ meje. Ní ọjọ́ kinni àjọ̀dún náà ẹ óo máa ní àpèjọ mímọ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan. Kí ẹ máa fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù meji, ati àgbò kan ati ọ̀dọ́ àgbò meje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí wọn kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ sísun sí OLUWA. Ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ óo rú pẹlu wọn ni ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò, ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta òṣùnwọ̀n efa fún akọ mààlúù kan, ati ìdámárùn-ún òṣùnwọ̀n efa fún àgbò kan, ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa fún ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan; ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fun yín. Ẹ óo máa rú àwọn ẹbọ wọnyi yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ojoojumọ. Báyìí ni ẹ óo ṣe rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA ní ojoojumọ fún ọjọ́ meje náà yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ. Ní ọjọ́ keje ẹ óo máa ní àpèjọ mímọ́, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan. “Ní ọjọ́ kinni àjọ̀dún ìkórè, nígbà tí ẹ óo bá mú ẹbọ ohun jíjẹ ti ọkà titun wá fún OLUWA, ẹ óo máa ní àpèjọ mímọ́, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan. Kí ẹ fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù meji, ati àgbò kan, ati ọ̀dọ́ àgbò meje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA. Ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ óo máa rú pẹlu wọn ni ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò: ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta òṣùnwọ̀n efa fún akọ mààlúù kan, ati ìdámárùn-ún òṣùnwọ̀n efa fún àgbò kan, ati ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa fún ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan; ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fun yín. Ẹ óo máa rú àwọn ẹbọ wọnyi pẹlu ẹbọ ohun mímu wọn, yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ojoojumọ. “Ní ọjọ́ kinni oṣù keje, ẹ óo máa ní àpèjọ mímọ́, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan. Ó jẹ́ ọjọ́ tí ẹ óo máa fun fèrè. Ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù kan, àgbò kan ati ọ̀dọ́ àgbò meje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ sísun, olóòórùn dídùn sí OLUWA. Ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ óo máa rú pẹlu wọn ni ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò, ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta òṣùnwọ̀n efa fún akọ mààlúù kan, ati ìdámárùn-ún òṣùnwọ̀n efa kan fún àgbò; ati ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa fún ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan, pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fun yín. Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ti ọjọ́ kinni oṣù, ati ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ pẹlu ẹbọ ohun mímu ojoojumọ, gẹ́gẹ́ bí ìlànà wọn. Wọ́n jẹ́ ẹbọ olóòórùn dídùn sí OLUWA. “Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù keje yìí, ẹ óo máa ní àpèjọ mímọ́, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. Kí ẹ fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù kan, ati àgbò kan ati ọ̀dọ́ àgbò meje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA. Ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ óo máa rú pẹlu wọn ni ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta òṣùnwọ̀n efa fún akọ mààlúù kan, ìdámárùn-ún òṣùnwọ̀n efa fún àgbò kan; ati ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa fún ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan, ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fun yín. Ẹ óo tún fi òbúkọ mìíràn rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ètùtù, ẹ óo sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ pẹlu.” “Ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù keje yìí, ẹ óo máa ní àpèjọ mímọ́, ẹ kò ní ṣe iṣẹ́ kankan fún ọjọ́ meje tí ẹ óo fi ṣe àjọ̀dún náà. Àjọ̀dún àyẹ́sí ni fún OLUWA. Ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mẹtala, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA. Ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ óo máa rú pẹlu wọn ni ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára tí a fi òróró pò, ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta òṣùnwọ̀n efa, fún akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan, ìdámárùn-ún òṣùnwọ̀n efa fún àgbò kọ̀ọ̀kan, ati ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa fún ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan; pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ. “Ní ọjọ́ keji, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mejila, àgbò meji, ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbààwọ́n rúbọ. Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi ìlànà ti ọjọ́ kinni, pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ. “Ní ọjọ́ kẹta, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mọkanla, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kan tí kò ní àbààwọ́n rúbọ. Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ìlànà ti ọjọ́ kinni; pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ. “Ní ọjọ́ kẹrin, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mẹ́wàá, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí kò ní àbààwọ́n rúbọ. Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi ìlànà ti ọjọ́ kinni; pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ. “Ní ọjọ́ karun-un, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mẹsan-an, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí kò ní àbààwọ́n rúbọ. Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà ti ọjọ́ kinni, pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ. “Ní ọjọ́ kẹfa, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mẹjọ, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí kò ní àbààwọ́n rúbọ. Ẹ óo rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà ti ọjọ́ kinni; pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ. “Ní ọjọ́ keje, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù meje, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbààwọ́n rúbọ. Ẹ óo rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà ti ọjọ́ kinni, pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú àwọn ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ. “Ní ọjọ́ kẹjọ ẹ óo máa ní àpèjọ mímọ́, ẹ kò sì ní gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan. Ẹ máa fi akọ mààlúù kan ati àgbò kan tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLÚWA. Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà ọjọ́ kinni; pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú àwọn ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ. “Àwọn ni àwọn ẹbọ tí ẹ óo máa rú sí OLUWA ní àwọn ọjọ́ àjọ̀dún yín, pẹlu ẹ̀jẹ́ yín, ẹbọ ọrẹ àtinúwá yín, ati ẹbọ sísun yín, ẹbọ ohun jíjẹ yín, ati ẹbọ ohun mímu yín, ati ẹbọ alaafia yín.” Mose sọ gbogbo rẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún un. Mose sọ fún àwọn olórí àwọn ẹ̀yà Israẹli àwọn ohun tí OLUWA pa láṣẹ: Bí ọmọkunrin kan bá bá OLUWA jẹ́jẹ̀ẹ́ tabi tí ó ṣe ìlérí láti yẹra fún ohunkohun, kò gbọdọ̀ yẹ ọ̀rọ̀ rẹ̀, bí ó ti wí ni ó gbọdọ̀ ṣe. Bí ọdọmọbinrin kan, tí ń gbé ilé baba rẹ̀ bá bá OLUWA jẹ́jẹ̀ẹ́ tabi tí ó ṣe ìlérí láti yẹra fún ohunkohun, ó gbọdọ̀ ṣe bí ó ti wí, àfi bí baba rẹ̀ bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà ati ìlérí tí ó ṣe. Bí baba rẹ̀ bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà ati ìlérí tí ó ṣe, nígbà tí ó gbọ́ ọ, ọdọmọbinrin náà kò ní san ẹ̀jẹ́ náà, OLUWA yóo dáríjì í nítorí pé baba rẹ̀ ni kò gbà á láàyè láti san ẹ̀jẹ́ rẹ̀. Bí ọmọbinrin kan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́, bóyá ó ti ọkàn rẹ̀ wá tabi kò ti ọkàn rẹ̀ wá, tí ó sì lọ ilé ọkọ lẹ́yìn ẹ̀jẹ́ tí ó jẹ́, ó níláti ṣe gbogbo ohun tí ó ti jẹ́jẹ̀ẹ́, àfi bí ọkọ rẹ̀ bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà ní ọjọ́ tí ó gbọ́ ọ. Bí ọkọ rẹ̀ bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà, ọmọbinrin náà kò ní san ẹ̀jẹ́ náà. OLUWA yóo dáríjì í nítorí pé ọkọ rẹ̀ ni kò gbà á láàyè láti san ẹ̀jẹ́ rẹ̀. Obinrin tí ó bá jẹ́ opó ati obinrin tí ó ti kọ ọkọ rẹ̀ gbọdọ̀ san ẹ̀jẹ́ wọn. Wọ́n sì gbọdọ̀ yẹra fún ohun gbogbo tí wọn bá ṣe ìlérí láti yẹra fún. Bí obinrin tí ó ní ọkọ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ tabi tí ó bá ṣe ìlérí láti yẹra fún ohunkohun, ó gbọdọ̀ san ẹ̀jẹ́ rẹ̀, àfi bí ọkọ rẹ̀ bá lòdì sí i nígbà tí ó gbọ́. Bí ọkọ rẹ̀ bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà, obinrin náà kò ní san ẹ̀jẹ́ náà. OLUWA yóo dáríjì í nítorí pé ọkọ rẹ̀ ni kò gbà á láàyè láti san ẹ̀jẹ́ rẹ̀. Ọkọ rẹ̀ ní àṣẹ láti gbà á láàyè láti san ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tabi kí ó kọ̀ fún un láti san án. Ṣugbọn bí ọkọ rẹ̀ kò bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà ní ọjọ́ tí ó gbọ́, ó níláti san gbogbo ẹ̀jẹ́ rẹ̀ nítorí pé ọkọ rẹ̀ kò lòdì sí i. Ṣugbọn bí ọkọ rẹ̀ bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà lẹ́yìn èyí, ọkọ náà ni yóo ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ obinrin náà nítorí pé kò jẹ́ kí ó san ẹ̀jẹ́ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ìlànà tí OLUWA pa láṣẹ fún Mose láàrin ọkọ ati aya ati láàrin baba ati ọmọ rẹ̀ obinrin, tí ń gbé ninu ilé rẹ̀. OLUWA sọ fún Mose pé, “Fìyà jẹ àwọn ará Midiani fún ohun tí wọ́n ṣe sí àwọn ọmọ Israẹli. Lẹ́yìn náà, o óo kú.” Mose bá sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ múra ogun kí á lè gbógun ti àwọn ará Midiani, kí á sì fìyà jẹ wọ́n fún ohun tí wọ́n ṣe sí OLUWA. Ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan yóo mú ẹgbẹrun eniyan wá fún ogun náà.” Nítorí náà láàrin ẹgbẹẹgbẹrun àwọn ọmọ Israẹli, ẹgbaafa (12,000) ọkunrin ni wọ́n dájọ láti lọ sójú ogun, ẹgbẹẹgbẹrun láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Mose sì rán wọn lọ sójú ogun lábẹ́ àṣẹ Finehasi ọmọ Eleasari alufaa, pẹlu àwọn ohun èlò mímọ́ ati fèrè fún ìdágìrì lọ́wọ́ rẹ̀. Wọ́n gbógun ti àwọn ará Midiani gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose, wọ́n sì pa gbogbo àwọn ọkunrin wọn. Wọ́n pa àwọn ọba Midiani maraarun pẹlu. Orúkọ wọn ni: Efi, Rekemu, Suri, Huri ati Reba. Wọ́n pa Balaamu ọmọ Beori pẹlu. Àwọn ọmọ Israẹli kó àwọn obinrin ati àwọn ọmọ Midiani lẹ́rú. Wọ́n kó gbogbo ẹran ọ̀sìn wọn ati gbogbo agbo ẹran wọn ati gbogbo ohun ìní wọn. Wọ́n fi iná sun gbogbo ìlú wọn ati àwọn abúlé wọn, wọ́n kó gbogbo ìkógun: eniyan ati ẹranko. Wọ́n kó wọn wá sọ́dọ̀ Mose ati Eleasari ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, ní òdìkejì odò Jọdani, lẹ́bàá Jẹriko. Mose, Eleasari ati àwọn olórí jáde lọ pàdé àwọn ọmọ ogun náà lẹ́yìn ibùdó. Mose bínú sí àwọn olórí ogun náà ati sí olórí ẹgbẹẹgbẹrun ati olórí ọgọọgọrun-un. Ó bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ dá àwọn obinrin wọnyi sí? Ṣé ẹ ranti pé àwọn ni wọ́n tẹ̀lé ìmọ̀ràn Balaamu tí wọ́n sì mú àwọn ọmọ Israẹli ṣẹ̀ sí OLUWA ní Peori, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yìí ni àjàkálẹ̀ àrùn ṣe bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ Israẹli? Nítorí náà ẹ pa gbogbo àwọn ọdọmọkunrin wọn, ati àwọn obinrin tí wọn ti mọ ọkunrin. Ṣugbọn kí ẹ dá àwọn ọdọmọbinrin tí wọn kò tíì mọ ọkunrin sí, kí ẹ fi wọ́n ṣe aya fún ara yín. Ǹjẹ́ nisinsinyii gbogbo àwọn tí ó bá ti paniyan tabi tí ó ti fọwọ́ kan òkú láàrin yín yóo dúró lẹ́yìn ibùdó fún ọjọ́ meje. Ní ọjọ́ kẹta ati ọjọ́ keje, àwọn ati obinrin tí wọ́n mú lójú ogun yóo ṣe ìwẹ̀nùmọ́. Ẹ sì níláti fọ gbogbo aṣọ yín, ati gbogbo àwọn ohun èlò tí a fi awọ ṣe, tabi irun ewúrẹ́, tabi igi.” Eleasari bá sọ fún wọn pé, “Ẹ gbọ́ ìlànà tí OLUWA ti fi lélẹ̀ láti ẹnu Mose. Gbogbo wúrà, fadaka, idẹ, irin ati tánńganran ati òjé, àní, gbogbo ohun tí kò bá ti lè jóná ni a óo mú la iná kọjá, kí á lè sọ wọ́n di mímọ́; a óo sì fi omi ìwẹ̀nùmọ́ fọ àwọn ohun èlò tí wọn bá lè jóná. Ní ọjọ́ keje, ẹ níláti fọ aṣọ yín, kí ẹ sì di mímọ́, lẹ́yìn náà, ẹ óo pada wá sí ibùdó.” OLUWA sọ fún Mose pé, “Ìwọ, Eleasari ati àwọn olórí, ẹ ka gbogbo ìkógun tí ẹ kó, ati eniyan ati ẹranko. Pín gbogbo ìkógun náà sí meji, kí apákan jẹ́ ti àwọn tí wọ́n lọ sójú ogun, kí apá keji sì jẹ́ ti àwọn ọmọ Israẹli yòókù. Yọ apákan sílẹ̀ fún OLUWA lára ti àwọn tí wọ́n lọ sójú ogun, ninu ẹẹdẹgbẹta tí o bá kà ninu eniyan ati mààlúù ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati ẹran ọ̀sìn, ọ̀kan jẹ́ ti OLUWA. Yọ ọ́ lára ìkógun wọn kí o sì kó wọn fún Eleasari alufaa gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sí OLUWA. Lára ìdajì tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Israẹli, mú ẹyọ kan ninu araadọta ninu eniyan ati mààlúù ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati ẹran ọ̀sìn; kí o sì kó wọn fún àwọn ọmọ Lefi tí ń ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́ OLUWA.” Mose ati Eleasari sì ṣe bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún wọn. Ìkógun tí ó kù ninu àwọn tí àwọn ọmọ ogun kó bọ̀ láti ojú ogun jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹrinlelọgbọn ó dín ẹgbẹẹdọgbọn (675,000) aguntan. Ẹgbaa mẹrindinlogoji (72,000) mààlúù. Ọ̀kẹ́ mẹta ó lé ẹgbẹrun (61,000) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Àwọn ọdọmọbinrin tí kò tíì mọ ọkunrin jẹ́ ẹgbaa mẹrindinlogun (32,000). Ìdajì rẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ ogun jẹ́ ẹgbaa mejidinlaadọsan-an ó lé ẹẹdẹgbẹjọ (337,500) aguntan. Ìpín ti OLUWA ninu rẹ̀ jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó dín mẹẹdọgbọn (675). Mààlúù jẹ́ ẹgbaa mejidinlogun (36,000), ìpín ti OLUWA ninu rẹ̀ jẹ́ mejilelaadọrin. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ jẹ́ ẹgbaa mẹẹdogun ó lé ẹẹdẹgbẹta (30,500), ìpín ti OLUWA ninu rẹ̀ jẹ́ mọkanlelọgọta. Àwọn eniyan sì jẹ́ ẹgbaajọ (16,000), ìpín ti OLUWA jẹ́ mejilelọgbọn. Mose kó ìpín ti OLUWA fún Eleasari alufaa gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un. Ìdajì yòókù, tí ó jẹ́ ìpín àwọn ọmọ Israẹli tí kò lọ sójú ogun, jẹ́ ẹgbaa mejidinlaadọsan-an ó lé ẹẹdẹgbẹjọ (337,500) aguntan. Ẹgbaa mejidinlogun (36,000) mààlúù. Ẹgbaa mẹẹdogun ó lé ẹẹdẹgbẹta (30,500) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Àwọn eniyan sì jẹ́ ẹgbaa mẹjọ (16,000). Ninu wọn, Mose mú ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu araadọta ninu àwọn eniyan ati ẹranko, ó sì kó wọn fún àwọn ọmọ Lefi tí ń ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́ OLUWA, bí OLUWA ti pàṣẹ fún un. Lẹ́yìn náà ni àwọn olórí ogun àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹrun ati ọgọọgọrun-un tọ Mose wá, wọ́n wí pé, “A ti ka àwọn ọmọ ogun tí ó wà lábẹ́ wa, kò sí ẹni tí ó kú sójú ogun. Nítorí náà a mú ọrẹ ẹbọ: ohun ọ̀ṣọ́ wúrà, ẹ̀wọ̀n, ẹ̀gbà ọwọ́, òrùka, yẹtí, ati ìlẹ̀kẹ̀ wá fún OLUWA lára ìkógun wa, láti fi ṣe ẹbọ ètùtù fún wa níwájú OLUWA.” Mose ati Eleasari gba àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wúrà ati àwọn ohun ọ̀ṣọ́ mìíràn náà lọ́wọ́ wọn. Ìwọ̀n gbogbo ọrẹ ẹbọ tí àwọn olórí ogun náà mú wá jẹ́ ẹgbaajọ ó lé ẹẹdẹgbẹrin ó lé aadọta (16,750) ṣekeli. Àwọn ọmọ ogun tí wọn kì í ṣe olórí ogun ti kó ìkógun tiwọn. Mose ati Eleasari kó wúrà náà lọ sinu Àgọ́ Àjọ gẹ́gẹ́ bí ohun ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli níwájú OLUWA. Nígbà tí àwọn ọmọ Reubẹni ati àwọn ọmọ Gadi, tí wọ́n ní ẹran ọ̀sìn pupọ, rí ilẹ̀ Jaseri ati ilẹ̀ Gileadi pé ibẹ̀ dára fún àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, wọ́n wá siwaju Mose, ati Eleasari ati àwọn olórí àwọn eniyan, wọ́n ní, “Atarotu ati Diboni ati Jaseri ati Nimra ati Heṣiboni ati Eleale ati Sebamu ati Nebo ati Beoni, tí OLUWA ti ran àwọn ọmọ Israẹli lọ́wọ́ láti gbà jẹ́ ilẹ̀ tí ó dára fún ẹran ọ̀sìn, àwa iranṣẹ yín sì ní ẹran ọ̀sìn pupọ. Nítorí náà, àwa bẹ̀ yín, ẹ fún wa ní ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ìní wa, ẹ má kó wa sọdá odò Jọdani.” Mose bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Ṣé ẹ fẹ́ jókòó níhìn-ín kí àwọn arakunrin yín máa lọ jagun ni? Kí ló dé tí ẹ fi mú ọkàn àwọn ọmọ Israẹli rẹ̀wẹ̀sì kí wọ́n má baà rékọjá lọ sinu ilẹ̀ tí OLUWA fi fún wọn? Bẹ́ẹ̀ ni àwọn baba yín ṣe nígbà tí mo rán wọn láti Kadeṣi Banea láti lọ ṣe amí ilẹ̀ náà. Wọ́n lọ títí dé àfonífojì Eṣikolu, wọ́n wo ilẹ̀ náà. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n pada dé, wọ́n mú kí ọkàn àwọn ọmọ Israẹli rẹ̀wẹ̀sì, kí wọn má lè lọ sí ilẹ̀ tí OLUWA ti fi fún wọn. Nítorí náà ni ibinu Ọlọrun ṣe ru sí wọn nígbà náà. Ó sì búra pé, ‘Ọ̀kan ninu àwọn tí ó ti ilẹ̀ Ijipti wá, láti ẹni ogún ọdún sókè kò ní rí ilẹ̀ náà tí mo ṣèlérí fún Abrahamu, fún Isaaki ati fún Jakọbu, nítorí pé wọn kò fi tọkàntọkàn ṣe tèmi.’ Àfi Kalebu ọmọ Jefune, ọmọ Kenisi ati Joṣua ọmọ Nuni, nítorí pé wọ́n fi tọkàntọkàn ṣe tèmi. Ibinu OLUWA ru sí àwọn ọmọ Israẹli, ó sì mú wọn rìn kiri ninu aṣálẹ̀ fún ogoji ọdún títí gbogbo àwọn tí wọ́n ṣe burúkú níwájú OLUWA fi kú tán. Nisinsinyii, ẹ̀yin ìran ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí dìde gẹ́gẹ́ bí àwọn baba ńlá yín láti mú kí inú bí OLUWA gidigidi sí Israẹli. Bí ẹ̀yin ẹ̀yà Reubẹni ati ẹ̀yà Gadi bá pada lẹ́yìn OLUWA, yóo kọ àwọn eniyan wọnyi sílẹ̀ sinu aṣálẹ̀. A jẹ́ pé ẹ̀yin ni ẹ fa ìparun wọn.” Wọ́n dá Mose lóhùn pé, “A óo kọ́ ilé fún àwọn ẹran ọ̀sìn wa níhìn-ín ati ìlú olódi fún àwọn ọmọ wa. Ṣugbọn àwa tìkarawa yóo di ihamọra ogun wa, a óo sì ṣáájú ogun fún àwọn yòókù títí wọn yóo fi gba ilẹ̀ ìní tiwọn. Ṣugbọn àwọn ọmọ wa yóo máa gbé ninu ìlú olódi níhìn-ín kí àwọn eniyan ilẹ̀ náà má baà yọ wọ́n lẹ́nu. A kò ní pada sí ilẹ̀ wa títí olukuluku àwọn ọmọ Israẹli yóo fi ní ilẹ̀ ìní tirẹ̀. A kò ní bá wọn pín ninu ilẹ̀ òdìkejì odò Jọdani nítorí pé a ti ní ilẹ̀ ìní tiwa ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani níhìn-ín.” Mose bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Bí nǹkan tí ẹ sọ yìí bá ti ọkàn yín wá, tí ẹ bá di ihamọra ogun yín níwájú OLUWA, tí àwọn ọmọ ogun yín sì ṣetán láti ré odò Jọdani kọjá ní àṣẹ OLUWA láti gbógun ti àwọn ọ̀tá wa títí OLUWA yóo fi pa wọ́n run, tí yóo sì gba ilẹ̀ náà, lẹ́yìn náà, ẹ lè pada nítorí pé ẹ ti ṣe ẹ̀tọ́ yín sí OLUWA ati sí àwọn arakunrin yín. Ilẹ̀ yìí yóo sì máa jẹ́ ìní yín pẹlu àṣẹ OLUWA. Ṣugbọn bí ẹ kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA. Ẹ jẹ́ kí ó da yín lójú pé ẹ kò ní lọ láì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín. Ẹ lọ kọ́ àwọn ìlú fún àwọn ọmọ yín ati ilé fún àwọn ẹran ọ̀sìn yín, kí ẹ sì ṣe ohun tí ẹ ṣèlérí.” Àwọn ọmọ Reubẹni ati Gadi sì dá Mose lóhùn, wọ́n ní, “Àwọn ọmọ wa, àwọn aya wa, àwọn mààlúù wa ati aguntan wa yóo wà ní àwọn ìlú Gileadi, ṣugbọn a ti ṣetán láti lọ sí ojú ogun nípa àṣẹ OLUWA. A óo ré odò Jọdani kọjá láti jagun gẹ́gẹ́ bí o ti sọ.” Mose bá pàṣẹ fún Eleasari alufaa, ati fún Joṣua ọmọ Nuni ati fún àwọn olórí àwọn ẹ̀yà Israẹli nípa wọn, ó ní, “Bí àwọn ọmọ Reubẹni ati Gadi bá bá yín ré odò Jọdani kọjá láti jagun níwájú OLUWA, bí wọ́n bá sì ràn yín lọ́wọ́ láti gba ilẹ̀ náà, ẹ óo fún wọn ní ilẹ̀ Gileadi gẹ́gẹ́ bí ìní wọn. Ṣugbọn bí wọn kò bá bá yín ré odò Jọdani kọjá, tí wọn kò sì lọ sí ojú ogun pẹlu yín, wọn óo gba ìpín ilẹ̀ ìní tiwọn ní Kenaani bíi àwọn ọmọ Israẹli yòókù.” Àwọn ọmọ Gadi ati àwọn ọmọ Reubẹni dáhùn, wọ́n ní, “A óo ṣe ohun tí OLUWA bá pa láṣẹ. Nípa àṣẹ rẹ̀ ni a óo ré odò Jọdani kọjá, a óo lọ jagun ní ilẹ̀ Kenaani, kí ilẹ̀ ìhà ìlà oòrùn Jọdani lè jẹ́ tiwa.” Mose bá fi ilẹ̀ Sihoni, ọba àwọn ará Amori, ilẹ̀ Ogu, ọba Baṣani ati àwọn ilẹ̀ ati àwọn ìlú tí ó yí wọn ká fún àwọn ọmọ Gadi, àwọn ọmọ Reubẹni ati ìdajì ẹ̀yà Manase ọmọ Josẹfu. Àwọn ọmọ Gadi sì tún àwọn ìlú olódi wọnyi kọ́: Diboni, Atarotu ati Aroeri, ati Atirotu Ṣofani, Jaseri, Jogibeha, ati Beti Nimra, Beti Harani, àwọn ìlú olódi ati ilé fún àwọn aguntan. Àwọn ọmọ Reubẹni tún àwọn ìlú wọnyi kọ́: Heṣiboni, Eleale, Kiriataimu, Nebo, Baali Meoni (wọ́n yí orúkọ ìlú yìí pada) ati Sibima. Wọ́n sì fún àwọn ìlú tí wọn tún kọ́ ní orúkọ mìíràn. Àwọn ọmọ Makiri tíí ṣe ẹ̀yà Manase gbógun ti àwọn ará Amori tí ó wà ní Gileadi, wọ́n lé wọn jáde, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn. Nítorí náà Mose fi ilẹ̀ Gileadi fún àwọn ọmọ Makiri láti inú ẹ̀yà Manase, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. Jairi ọmọ Manase gbógun ti àwọn ìlú kan, ó sì gbà wọ́n. Ó sọ orúkọ wọn ní Hafoti Jairi. Noba gbógun ti Kenati ati àwọn ìletò rẹ̀, ó sì gbà wọ́n. Ó sọ orúkọ rẹ̀ ní Noba tíí ṣe orúkọ ara rẹ̀. Ibi tí àwọn ọmọ Israẹli pàgọ́ sí ninu ìrìn àjò wọn láti ìgbà tí wọn ti kúrò ní Ijipti lábẹ́ àṣẹ Mose ati Aaroni nìwọ̀nyí: (Orúkọ gbogbo ibi tí wọ́n pàgọ́ sí ni Mose ń kọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA.) Àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Ramesesi ní Ijipti ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù kinni, ní ọjọ́ keji Àjọ̀dún Ìrékọjá pẹlu ọwọ́ agbára OLUWA, níṣojú àwọn ará Ijipti, tí wọn ń sin òkú àwọn àkọ́bí wọn tí OLUWA pa, OLUWA fihàn pé òun ní agbára ju oriṣa àwọn ará Ijipti lọ. Àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Ramesesi, wọ́n lọ pàgọ́ sí Sukotu. Wọ́n kúrò ní Sukotu, wọ́n lọ pàgọ́ sí Etamu tí ó wà létí aṣálẹ̀. Láti ibẹ̀ wọ́n pada sẹ́yìn lọ sí Pi Hahirotu tí ó wà níwájú Baali Sefoni, wọ́n pàgọ́ siwaju Migidoli. Wọ́n kúrò níwájú Pi Hahirotu, wọ́n la ààrin òkun kọjá lọ sinu aṣálẹ̀. Lẹ́yìn ìrìn ọjọ́ mẹta ninu aṣálẹ̀ Etamu, wọ́n pàgọ́ sí Mara. Wọ́n kúrò ní Mara, wọ́n lọ pàgọ́ sí Elimu níbi tí orísun omi mejila ati aadọrin igi ọ̀pẹ wà. Wọ́n kúrò ní Elimu, wọ́n lọ pàgọ́ sí etí Òkun Pupa. Wọ́n kúrò níbẹ̀, wọ́n lọ pàgọ́ sí aṣálẹ̀ Sini. Wọ́n kúrò ní aṣálẹ̀ Sini, wọ́n lọ pàgọ́ sí Dofika. Wọ́n kúrò ní Dofika, wọ́n lọ pàgọ́ sí Aluṣi. Wọ́n kúrò ní Aluṣi, wọ́n lọ pàgọ́ sí Refidimu níbi tí wọn kò ti rí omi mu. Wọ́n kúrò ní Refidimu lọ sí aṣálẹ̀ Sinai. Láti aṣálẹ̀ Sinai wọ́n lọ sí Kiburotu Hataafa. Láti Kiburotu Hataafa wọ́n lọ sí Haserotu. Láti Haserotu wọ́n lọ sí Ritima. Láti Ritima wọ́n lọ sí Rimoni Peresi. Láti Rimoni Peresi wọ́n lọ sí Libina. Láti Libina wọ́n lọ sí Risa. Láti Risa wọ́n lọ sí Kehelata. Láti Kehelata wọ́n lọ sí Òkè Ṣeferi. Láti Òkè Ṣeferi wọ́n lọ sí Harada. Láti Harada wọ́n lọ sí Makihelotu. Láti Makihelotu wọ́n lọ sí Tahati. Láti Tahati wọ́n lọ sí Tẹra. Láti Tẹra wọ́n lọ sí Mitika. Láti Mitika wọ́n lọ sí Haṣimona. Láti Haṣimona wọ́n lọ sí Moserotu. Láti Moserotu wọ́n lọ sí Bene Jaakani. Láti Bene Jaakani wọ́n lọ sí Hori Hagidigadi. Láti Hori Hagidigadi wọ́n lọ sí Jotibata. Láti Jotibata wọ́n lọ sí Abirona. Láti Abirona wọ́n lọ sí Esiongeberi. Láti Esiongeberi wọ́n lọ sí aṣálẹ̀ Sini, tíí ṣe Kadeṣi. Láti Kadeṣi wọ́n lọ sí Òkè Hori, lẹ́bàá ilẹ̀ Edomu. Aaroni alufaa gun Òkè Hori lọ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún un, níbẹ̀ ni ó sì kú sí ní ọjọ́ kinni oṣù karun-un, ogoji ọdún lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Ijipti. Aaroni jẹ́ ẹni ọdún mẹtalelọgọfa (123) nígbà tí ó kú ní Òkè Hori. Ọba ìlú Aradi, ní ilẹ̀ Kenaani, tí ń gbé Nẹgẹbu gbúròó pé àwọn ọmọ Israẹli ń bọ̀. Wọ́n kúrò ní Òkè Hori wọn lọ sí Salimona. Wọ́n kúrò ní Salimona wọ́n lọ sí Punoni. Láti Punoni wọ́n lọ sí Obotu. Láti Obotu wọ́n lọ sí Òkè Abarimu ní agbègbè Moabu. Láti Iyimu wọ́n lọ sí Diboni Gadi. Láti Diboni Gadi wọ́n lọ sí Alimoni Dibilataimu. Láti Alimoni Dibilataimu wọ́n lọ sí Òkè Abarimu níwájú Nebo. Láti Òkè Abarimu wọ́n lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá odò Jọdani létí Jẹriko. Wọ́n sì pàgọ́ wọn sí ẹ̀bá odò Jọdani láti Beti Jeṣimotu títí dé Abeli Ṣitimu ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu. OLUWA sọ fún Mose ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá odò Jọdani létí Jẹriko pé kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Nígbà tí ẹ bá ré odò Jọdani kọjá sí ilẹ̀ Kenaani, ẹ gbọdọ̀ lé gbogbo àwọn eniyan tí ń gbé ilẹ̀ náà kúrò. Ẹ run gbogbo àwọn oriṣa tí wọ́n fi òkúta ati irin ṣe ati gbogbo ilé oriṣa wọn. Kí ẹ gba ilẹ̀ náà kí ẹ sì máa gbé inú rẹ̀, nítorí pé mo ti fun yín gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní yín. Gègé ni kí ẹ fi pín ilẹ̀ náà fún àwọn ẹ̀yà Israẹli. Fún àwọn tí ó pọ̀ ní ilẹ̀ pupọ, sì fún àwọn tí ó kéré ní ilẹ̀ kékeré. Ilẹ̀ tí gègé olukuluku bá mú ni yóo jẹ́ tirẹ̀, láàrin àwọn ẹ̀yà yín ni ẹ óo ti pín ilẹ̀ náà. Ṣugbọn bí ẹ kò bá lé gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náà kúrò, àwọn tí ó bá kù yóo di ẹ̀gún ní ojú yín ati ẹ̀gún ní ìhà yín, wọn yóo sì máa yọ yín lẹ́nu lórí ilẹ̀ náà. Bí ẹ kò bá lé gbogbo wọn jáde, ohun tí mo ti pinnu láti ṣe sí wọn, ẹ̀yin ni n óo ṣe é sí.” OLUWA sọ fún Mose pé, “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ Kenaani tí mo fun yín, gbogbo ilẹ̀ náà ni yóo jẹ́ tiyín. Àwọn ààlà ilẹ̀ yín nìwọ̀nyí.’ Ilẹ̀ yín ní ìhà gúsù yóo bẹ̀rẹ̀ láti aṣálẹ̀ Sini lẹ́bàá ààlà Edomu. Ààlà yín ní ìhà gúsù yóo jẹ́ láti òpin Òkun-Iyọ̀ ní ìlà oòrùn. Yóo sì yí láti ìhà gúsù lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Akirabimu, yóo sì la aṣálẹ̀ Sini kọjá lọ títí dé ìhà gúsù Kadeṣi Banea ati títí dé Hasari Adari ati títí dé Asimoni. Yóo sì yí láti Asimoni lọ dé odò Ijipti, òkun ni yóo sì jẹ́ òpin rẹ̀. “Ní ìhà ìwọ̀ oòrùn Òkun ni yóo jẹ́ ààlà yín. “Ní ìhà àríwá, ààlà yín yóo gba ẹ̀gbẹ́ òkun ńlá lọ títí dé Òkè Hori. Láti ibẹ̀ lọ dé ẹnu ibodè Hamati, títí dé Sedadi, Sifironi ati Hasari Enani. “Ààlà ìhà ìlà oòrùn yín yóo gba ẹ̀gbẹ́ Hasari Enani lọ sí Ṣefamu. Yóo lọ sí ìhà gúsù sí Ribila ní ìhà ìlà oòrùn Aini títí lọ sí àwọn òkè tí wọ́n wà létí ìhà ìlà oòrùn Òkun-Kinereti. Láti ibẹ̀ lọ sí ìhà gúsù lẹ́bàá odò Jọdani, yóo parí sí Òkun-Iyọ̀. Àwọn ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ yín.” Mose sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Èyí ni ilẹ̀ tí ẹ óo fi gègé pín. Ilẹ̀ tí OLUWA yóo fún àwọn ẹ̀yà mẹsan-an ààbọ̀ yòókù. Àwọn ẹ̀yà Reubẹni ati ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase ti gba ilẹ̀ tiwọn, tí a pín gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn. ní ìhà ìlà oòrùn Jọdani ní òdìkejì Jẹriko. Wọ́n sì ti pín in ní ìdílé-ìdílé.” OLUWA sọ fún Mose pé, “Eleasari alufaa ati Joṣua ọmọ Nuni ni yóo pín ilẹ̀ náà fun yín. Mú olórí kọ̀ọ̀kan ninu ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan láti ràn wọ́n lọ́wọ́.” Àwọn olórí náà nìwọ̀nyí: láti inú ẹ̀yà Juda, a yan Kalebu ọmọ Jefune. Láti inú ẹ̀yà Simeoni, a yan Ṣemueli ọmọ Amihudu. Láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, a yan Elidadi ọmọ Kisiloni. Láti inú ẹ̀yà Dani, a yan Buki ọmọ Jogili. Láti inú ẹ̀yà Manase, a yan Hanieli ọmọ Efodu. Láti inú ẹ̀yà Efuraimu, a yan Kemueli ọmọ Ṣifitani. Láti inú ẹ̀yà Sebuluni, a yan Elisafani ọmọ Parinaki. Láti inú ẹ̀yà Isakari, a yan Palitieli ọmọ Asani. Láti inú ẹ̀yà Aṣeri, a yan Ahihudu ọmọ Ṣelomi. Láti inú ẹ̀yà Nafutali, a yan Pedaheli ọmọ Amihudu. Àwọn ni OLUWA pàṣẹ fún láti pín ilẹ̀ ìní náà fún àwọn ọmọ Israẹli ní ilẹ̀ Kenaani. Ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní ìhà ìlà oòrùn Jọdani ní òdìkejì Jẹriko, OLUWA sọ fún Mose pé, “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé ninu ilẹ̀ ìní wọn, kí wọ́n fún àwọn ọmọ Lefi ní àwọn ìlú tí wọn yóo máa gbé, kí wọ́n sì fún wọn ní ilẹ̀ pápá yíká àwọn ìlú wọnyi. Àwọn ìlú náà yóo jẹ́ ti àwọn ọmọ Lefi, wọn óo máa gbébẹ̀. Ilẹ̀ tí ó yí àwọn ìlú náà ká yóo wà fún àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ati mààlúù wọn. Kí ilẹ̀ pápá tí yóo yí àwọn ìlú tí ẹ óo fún àwọn ọmọ Lefi ká jẹ́ ẹgbẹrun igbọnwọ láti ibi odi ìlú wọn siwaju. Lẹ́yìn odi ìlú kọ̀ọ̀kan, kí ẹ wọn ẹgbaa igbọnwọ ní ìhà kọ̀ọ̀kan ní ìhà ìlà oòrùn, ati ìhà gúsù, ati ìhà ìwọ̀ oòrùn, ati ìhà àríwá; kí ìlú wà ní ààrin. Ilẹ̀ tí ẹ wọ̀n yìí ni yóo jẹ́ ibùjẹ fún àwọn ẹran ọ̀sìn. Ninu àwọn ìlú tí ẹ óo fún àwọn ọmọ Lefi, mẹfa ninu wọn yóo jẹ́ ìlú ààbò tí ẹni tí ó bá ṣèèṣì paniyan lè sá lọ. Lẹ́yìn ìlú mẹfa yìí, ẹ óo tún fún wọn ní ìlú mejilelogoji pẹlu ilẹ̀ tí ó yí wọn ká. Gbogbo ìlú tí ẹ óo fún wọn yóo jẹ́ mejidinlaadọta pẹlu ilẹ̀ pápá tí ó yí wọn ká. Bí ilẹ̀ ìní olukuluku ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli bá ti tóbi tó, bẹ́ẹ̀ ni iye ìlú tí wọn yóo fi sílẹ̀ fún àwọn ọmọ Lefi yóo pọ̀ tó.” OLUWA sọ fún Mose pé, “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, nígbà tí wọ́n bá ré Jọdani kọjá sí ilẹ̀ Kenaani, kí wọ́n yan ìlú mẹfa fún ìlú ààbò tí ẹni tí ó bá ṣèèṣì paniyan lè sá lọ. Yóo jẹ́ ibi ààbò fún ẹni tí ó paniyan, bí arakunrin ẹni tí ó pa bá fẹ́ gbẹ̀san, nítorí pé ẹ kò gbọdọ̀ pa ẹni tí ó bá ṣèèṣì paniyan títí yóo fi dúró níwájú ìjọ eniyan Israẹli fún ìdájọ́. Ẹ óo yan ìlú mẹfa fún èyí. Mẹta ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani ati mẹta ní ilẹ̀ Kenaani. Wọn yóo jẹ́ ìlú ààbò fún àwọn ọmọ Israẹli tabi àwọn àlejò tí ó wà láàrin wọn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì paniyan lè sá lọ sibẹ. “Ṣugbọn bí ẹnìkan bá fi ohun èlò irin lu arakunrin rẹ̀ tí ẹni náà sì kú, apànìyàn ni ẹni tí ó fi ohun èlò irin lu arakunrin rẹ̀, pípa ni wọn yóo pa òun náà. Bí ó bá sọ òkúta lu arakunrin rẹ̀ tí arakunrin náà sì kú, apànìyàn ni; pípa ni wọn yóo pa òun náà. Tabi tí ó bá fi ohun ìjà olóró lu arakunrin rẹ̀ tí ẹni náà sì kú, apànìyàn ni, pípa ni wọn yóo pa òun náà. Arakunrin ẹni tí a pa ni yóo pa apànìyàn náà nígbà tí ó bá rí i. “Bí ẹnìkan bá kórìíra arakunrin rẹ̀, tí ó sì fi ohun ìjà gún un, tabi tí ó ju nǹkan lù ú láti ibi tí ó sápamọ́ sí, tí ẹni náà bá kú, tabi tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ lù ú pẹlu ibinu tí ẹni náà sì kú. Apànìyàn náà yóo jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn, yóo sì kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Arakunrin ẹni tí ó pa ni yóo pa apànìyàn náà nígbà tí ó bá rí i. “Ṣugbọn bí ẹnìkan bá ṣèèṣì paniyan, tí kì í ṣe pẹlu ìríra, kì báà jẹ́ pé ó fi ohun ìjà gún un, tabi kí ó ṣèèṣì ju nǹkan lù ú, tabi bí ẹnìkan bá ṣèèṣì sọ òkúta láì wo ibi tí ó sọ òkúta náà sí, tí òkúta náà sì pa eniyan tí kì í ṣe pé ó ti fẹ́ pa olúwarẹ̀ tẹ́lẹ̀, tí kò sì kórìíra rẹ̀, kí ìjọ eniyan Israẹli ṣe ìdájọ́ láàrin ẹni tí ó ṣèèṣì paniyan ati arakunrin ẹni tí wọ́n pa, tí ó fẹ́ gbẹ̀san, gẹ́gẹ́ bí ìlànà yìí. Kí ìjọ eniyan gba ẹni tí ó paniyan náà lọ́wọ́ olùgbẹ̀san, kí wọ́n mú un pada lọ sí ìlú ààbò rẹ̀. Níbẹ̀ ni yóo sì máa gbé títí tí olórí alufaa tí a fi òróró yàn yóo fi kú. Ṣugbọn bí apànìyàn náà bá rékọjá odi ìlú ààbò rẹ̀, tí arakunrin ẹni tí ó pa bá rí i tí ó sì pa á, olùgbẹ̀san náà kì yóo ní ẹ̀bi; nítorí pé apànìyàn náà gbọdọ̀ dúró ní ìlú ààbò rẹ̀ títí tí olórí alufaa yóo fi kú, lẹ́yìn náà, ó lè pada sí ilẹ̀ ìní rẹ̀. Èyí yóo jẹ́ ìlànà ati òfin fun yín láti ìrandíran yín níbikíbi tí ẹ bá ń gbé. “Kí ẹ tó pa ẹnikẹ́ni tí ó bá paniyan, ẹlẹ́rìí meji gbọdọ̀ jẹ́rìí sí i pé nítòótọ́ ni olúwarẹ̀ paniyan. Ẹ̀rí eniyan kan kò tó fún ẹjọ́ apànìyàn. Kí ẹ má ṣe gba owó ìtanràn lọ́wọ́ ẹni tí ó jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn, pípa ni ẹ gbọdọ̀ pa òun náà. Bí apànìyàn kan bá sá lọ sí ìlú ààbò, ẹ kò gbọdọ̀ gba owó ìtanràn lọ́wọ́ rẹ̀, kí ó baà lè pada sí ilẹ̀ ìní rẹ̀ ṣáájú ikú olórí alufaa. Bí ẹ bá ṣe èyí, ẹ óo sọ ilẹ̀ yín di aláìmọ́ nítorí pé ìpànìyàn a máa sọ ilẹ̀ di àìmọ́. Ikú apànìyàn nìkan ni ó sì lè ṣe ètùtù fún ìwẹ̀nùmọ́ ilẹ̀ tí ó ti di àìmọ́ nípa ìpànìyàn. Ẹ má ṣe sọ ilẹ̀ tí ẹ̀ ń gbé di aláìmọ́, àní, ilẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli láàrin àwọn tí èmi OLUWA ń gbé.” Àwọn olórí ìdílé àwọn ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri ati ẹ̀yà Manase ọmọ Josẹfu, wá sọ́dọ̀ Mose ati àwọn olórí ẹ̀yà Israẹli, wọ́n ní, “OLUWA pàṣẹ fun yín pé kí ẹ fi gègé pín ilẹ̀ náà fún àwọn eniyan Israẹli. Ó sì pàṣẹ fun yín pé kí ẹ fi ilẹ̀-ìní arakunrin wa Selofehadi fún àwọn ọmọbinrin rẹ̀. Ṣugbọn bí wọ́n bá lọ́kọ lára ẹ̀yà Israẹli mìíràn, a ó gba ilẹ̀-ìní wọn kuro ninu ilẹ̀-ìní awọn baba wa, ilẹ̀-ìní wọn yóo jẹ́ ti ẹ̀yà àwọn ọkọ wọn, èyí yóo sì mú kí ilẹ̀ wa dínkù. Nígbà tí ọdún jubili bá kò, tí a óo dá gbogbo ilẹ̀-ìní pada fún àwọn tí wọ́n ni wọ́n, ilẹ̀-ìní àwọn ọmọbinrin Selofehadi yóo jẹ́ ti ẹ̀yà àwọn ọkọ wọn, èyí yóo sì mú kí ilẹ̀ tiwa dínkù.” Mose bá pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti wí fún un, pé, “Ohun tí ẹ̀yà Manase sọ dára, nítorí náà OLUWA wí pé àwọn ọmọbinrin Selofehadi ní ẹ̀tọ́ láti fẹ́ ẹnikẹ́ni tí ó wù wọ́n, ṣugbọn ó gbọdọ̀ jẹ́ láti inú ẹ̀yà wọn. Ilẹ̀-ìní ẹ̀yà kan kò gbọdọ̀ di ti ẹ̀yà mìíràn, ilẹ̀ ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ wà ní ìkáwọ́ rẹ̀. Obinrin tí ó bá ní ilẹ̀-ìní gbọdọ̀ fẹ́ ọkọ láàrin ẹ̀yà rẹ̀, kí olukuluku àwọn ọmọ Israẹli lè máa jogún ilẹ̀ ìní baba rẹ̀.” Ilẹ̀-ìní ẹ̀yà kan kò gbọdọ̀ di ti ẹ̀yà mìíràn, ilẹ̀ ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ wà ní ìkáwọ́ rẹ̀. Àwọn ọmọbinrin Selofehadi ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA fún Mose; Mahila, Tirisa, Hogila, Milika ati Noa fẹ́ ọkọ láàrin àwọn arakunrin baba wọn, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ. Wọ́n fẹ́ ọkọ láàrin ẹ̀yà Manase ọmọ Josẹfu, ilẹ̀-ìní wọn sì dúró ninu ẹ̀yà baba wọn. Àwọn ni ìlànà ati òfin tí OLUWA ti pa láṣẹ fún Mose fún àwọn ọmọ Israẹli, ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní ìhà ìlà oòrùn Jọdani, ní òdìkejì Jẹriko. Ọ̀rọ̀ tí Mose bá àwọn eniyan Israẹli sọ ninu aṣálẹ̀ nìyí, ní òdìkejì odò Jọdani, ní Araba tí ó kọjú sí Sufu, láàrin Parani, Tofeli, Labani, Haserotu ati Disahabu. Ìrìn ọjọ́ mọkanla ni láti Horebu dé Kadeṣi Banea, tí eniyan bá gba ọ̀nà òkè Seiri. Ní ọjọ́ kinni oṣù kọkanla, ní ogoji ọdún tí wọ́n ti kúrò ní Ijipti, ni Mose bá àwọn eniyan Israẹli sọ ohun tí OLUWA pàṣẹ fún un láti sọ fún wọn; lẹ́yìn tí ó ti ṣẹgun Sihoni, ọba àwọn ará Amori tí ń gbé Heṣiboni; ati Ogu, ọba àwọn ará Baṣani, tí ń gbé Aṣitarotu ati Edirei. Ní òdìkejì odò Jọdani, ní apá ìlà oòrùn, ní ilẹ̀ Moabu, ni Mose ti ṣe àlàyé àwọn òfin wọnyi. Ó ní, “OLUWA Ọlọrun wa sọ fún wa ní Horebu pé, a ti pẹ́ tó ní ẹsẹ̀ òkè náà. Ó ní kí á dìde, kí á bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí agbègbè olókè ti àwọn ará Amori, ati gbogbo agbègbè tí ó yí wọn ká ní Araba, ní àwọn agbègbè olókè ati ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, ati ilẹ̀ Nẹgẹbu, ati èyí tí ó wà létí òkun tí wọn ń pè ní Mẹditarenia, ilẹ̀ àwọn ará Kenaani ati Lẹbanoni, títí dé odò ńlá nnì, àní odò Yufurate. Ó ní, ‘Ẹ wò ó! Mo ti pèsè ilẹ̀ náà fun yín, ẹ lọ, kí ẹ sì gbà á; Èmi OLUWA ti búra láti fún Abrahamu ati Isaaki, ati Jakọbu, àwọn baba ńlá yín ati arọmọdọmọ wọn.’ ” “Mo sọ fun yín nígbà náà pé, èmi nìkan kò ní lè máa ṣe àkóso yín. OLUWA Ọlọrun yín ti sọ yín di pupọ, lónìí ẹ pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run. Kí OLUWA Ọlọrun àwọn baba ńlá yín jẹ́ kí ẹ tún pọ̀ jù báyìí lọ lọ́nà ẹgbẹrun. Kí ó sì bukun yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí fun yín. Báwo ni mo ṣe lè dá nìkan dàyàkọ ìnira yín ati ẹrù yín ati ìjà yín. Mo ní kí ẹ yan àwọn ọlọ́gbọ́n, tí wọ́n ní ìmọ̀ ati ìrírí láàrin ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, n óo sì fi wọ́n ṣe olórí yín. Ìdáhùn tí ẹ fún mi nígbà náà ni pé, ohun tí mo wí ni ó yẹ kí ẹ ṣe. Mo bá fi mú àwọn olórí olórí ninu àwọn ẹ̀yà yín, àwọn tí wọ́n gbọ́n tí wọ́n sì ní ìrírí, mo yàn wọ́n gẹ́gẹ́ bí olórí fun yín. Mo fi àwọn kan jẹ balogun lórí ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, àwọn mìíràn lórí ọgọọgọrun-un eniyan, àwọn mìíràn lórí araadọta eniyan; bẹ́ẹ̀ ni mo fi àwọn ẹlòmíràn jẹ balogun lórí eniyan mẹ́wàá mẹ́wàá, mo sì fi àwọn kan ṣe olórí ninu gbogbo ẹ̀yà yín. “Mo pàṣẹ fún àwọn adájọ́ yín nígbà náà, mo ní, ‘Ẹ máa gbọ́ ẹjọ́ àwọn arakunrin yín, kí ẹ sì máa ṣe ìdájọ́ òdodo láàrin eniyan ati arakunrin rẹ̀, tabi àlejò tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ojuṣaaju ninu ìdájọ́ yín; kì báà jẹ́ àwọn eniyan ńláńlá, kì báà jẹ́ àwọn mẹ̀kúnnù, bákan náà ni kí ẹ máa gbọ́ ẹjọ́ wọn. Ẹ kò gbọdọ̀ bẹ̀rù eniyan, nítorí Ọlọrun ni onídàájọ́. Bí ẹjọ́ kan bá le jù fun yín láti dá, ẹ kó o tọ̀ mí wá, n óo sì dá a.’ Gbogbo ohun tí ó yẹ kí ẹ ṣe nígbà náà ni mo pa láṣẹ fun yín. “Gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun wa ti pàṣẹ fún wa nígbà náà, a gbéra ní Horebu, a sì la àwọn aṣálẹ̀ ńláńlá tí wọ́n bani lẹ́rù kọjá, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ṣe rí i ní ojú ọ̀nà àwọn agbègbè olókè àwọn ará Amori; a sì dé Kadeṣi Banea. Mo sọ fun yín nígbà náà pé, ẹ ti dé agbègbè olókè àwọn ará Amori, tí OLUWA Ọlọrun wa fi fún wa, ilẹ̀ náà ni OLUWA Ọlọrun yín tẹ́ kalẹ̀ níwájú yín yìí, mo ní kí ẹ gbéra, kí ẹ lọ gbà á, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun àwọn baba ńlá yín ti sọ fun yín. Mo ní kí ẹ má bẹ̀rù rárá, kí ẹ má sì fòyà. “Gbogbo yín wá sọ́dọ̀ mi, ẹ sì wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á rán àwọn eniyan lọ ṣiwaju wa, láti lọ ṣe amí ilẹ̀ náà, kí wọ́n lè wá jábọ̀ fún wa, kí á lè mọ ọ̀nà tí ó yẹ kí á tọ̀, ati àwọn ìlú tí ó yẹ kí á wọ̀.’ “Ọ̀rọ̀ yín dára lójú mi, mo sì yan ọkunrin mejila láàrin yín, ọkunrin kọ̀ọ̀kan láàrin ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Wọ́n gbéra, wọ́n lọ sí agbègbè olókè náà, títí tí wọ́n fi dé àfonífojì Eṣikolu, tí wọ́n sì ṣe amí rẹ̀. Wọ́n ká ninu èso ilẹ̀ náà bọ̀, wọ́n sì jábọ̀ fún wa pé ilẹ̀ dáradára ni OLUWA Ọlọrun wa fi fún wa. “Sibẹsibẹ, ẹ kọ̀, ẹ kò lọ, ẹ ṣe orí kunkun sí àṣẹ tí OLUWA Ọlọrun yín pa fun yín. Ẹ bẹ̀rẹ̀ sí kùn ninu àgọ́ yín, ẹ ní, ‘Ọlọrun kò fẹ́ràn wa, ni ó ṣe kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti, kí ó lè kó wa lé àwọn ará Amori lọ́wọ́, kí wọ́n sì pa wá run. Kí ni a fẹ́ lọ ṣe níbẹ̀? Ojora ti mú wa, nítorí ọ̀rọ̀ tí àwọn arakunrin wa sọ fún wa, tí wọ́n ní àwọn ará ibẹ̀ lágbára jù wá lọ, wọ́n sì ṣígbọnlẹ̀ jù wá lọ. Àwọn ìlú wọn tóbi, wọ́n sì jẹ́ ìlú olódi, odi wọn ga kan ọ̀run, àwọn òmìrán ọmọ Anaki sì wà níbẹ̀!’ “Mo wí fun yín nígbà náà pé kí ẹ má ṣojo, kí ẹ má sì jẹ́ kí ẹ̀rù wọn bà yín. OLUWA Ọlọrun yín tí ń ṣáájú yín ni yóo jà fun yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti jà fun yín ní ilẹ̀ Ijipti, tí ẹ̀yin náà sì fi ojú ara yín rí i. Ninu aṣálẹ̀ ńkọ́? Ṣebí ẹ rí i bí OLUWA Ọlọrun yín ti gbé yín, bí baba tíí gbé ọmọ rẹ̀, ní gbogbo ọ̀nà tí ẹ tọ̀ títí tí ẹ fi dé ibi tí ẹ wà yìí. Sibẹsibẹ ẹ kò gba OLUWA Ọlọrun yín gbọ́, Ọlọrun tí ń lọ níwájú yín ninu ọ̀wọ̀n iná lóru, ati ninu ìkùukùu lọ́sàn-án, láti fi ọ̀nà tí ẹ óo máa tọ̀ hàn yín kí ó lè bá yín wá ibi tí ẹ óo pàgọ́ yín sí. “OLUWA gbọ́ ohun tí ẹ sọ, inú bí i, ó sì búra pé, ẹnikẹ́ni ninu ìran burúkú náà kò ní fi ojú kan ilẹ̀ dáradára tí òun ti búra pé òun óo fún àwọn baba yín; àfi Kalebu ọmọ Jefune ni yóo rí i. Òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni òun óo sì fún ní ilẹ̀ tí ó ti fi ẹsẹ̀ rẹ̀ tẹ̀, nítorí pé, ó fi tọkàntọkàn tẹ̀lé òun. OLUWA bínú sí èmi pàápàá nítorí tiyín, ó ní èmi náà kò ní dé ibẹ̀. Joṣua, ọmọ Nuni, tí ń ṣe iranṣẹ òun, ni yóo dé ilẹ̀ náà. Nítorí náà, ó ní kí n mú un lọ́kàn le, nítorí òun ni yóo jẹ́ kí Israẹli gba ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì jogún rẹ̀. Ọlọrun ní àwọn ọmọ yín kéékèèké, tí kò tíì mọ ire yàtọ̀ sí ibi, àwọn tí ẹ sọ pé wọn yóo bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín, àwọn ni wọn yóo dé ilẹ̀ náà, àwọn ni òun óo sì fi fún, ilẹ̀ náà yóo sì di ìní wọn. Ṣugbọn ní tiyín, ó ní kí ẹ yipada, kí ẹ sì máa lọ sinu aṣálẹ̀, ní apá ọ̀nà Òkun Pupa. “Nígbà náà, ẹ dá mi lóhùn, ẹ ní, ẹ ti ṣẹ̀ sí OLUWA, nítorí náà, ẹ óo dìde, ẹ óo sì lọ jagun, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun ti pa á láṣẹ fun yín. Olukuluku yín bá múra láti jagun, gbogbo èrò yín nígbà náà ni pé kò ní ṣòro rárá láti ṣẹgun àwọn tí wọn ń gbé agbègbè olókè náà. “OLUWA wí fún mi pé, ‘Kìlọ̀ fún wọn kí wọ́n má gòkè lọ jagun, nítorí pé n kò ní bá wọn lọ; bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àwọn ọ̀tá yóo ṣẹgun wọn.’ Mo sọ ohun tí OLUWA wí fun yín, ṣugbọn ẹ kọ̀, ẹ kò gbọ́. Ẹ ṣe oríkunkun sí àṣẹ OLUWA, ẹ sì lọ pẹlu ẹ̀mí ìgbéraga. Àwọn ará Amori tí wọn ń gbé agbègbè olókè náà bá jáde sí yín, wọ́n le yín bí oyin tíí lé ni, wọ́n sì pa yín ní ìpakúpa láti Seiri títí dé Horima. Nígbà tí ẹ pada dé, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí sọkún níwájú OLUWA, ṣugbọn OLUWA kò gbọ́ tiyín, bẹ́ẹ̀ ni kò fetí sí ẹkún yín. “Nítorí náà, gbogbo wa wà ní Kadeṣi fún ìgbà pípẹ́. “Nígbà tí ó yá, a pada sinu aṣálẹ̀ ní ọ̀nà Òkun Pupa, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún mi; a sì rìn káàkiri lórí òkè Seiri fún ọpọlọpọ ọjọ́. “OLUWA bá wí fún mi pé, ‘Ìrìn tí ẹ rìn káàkiri ní agbègbè olókè yìí tó gẹ́ẹ́; ẹ yipada sí apá àríwá.’ OLUWA ní kí n pàṣẹ pé, ‘Ilẹ̀ tí ẹ óo là kọjá yìí jẹ́ ilẹ̀ àwọn ọmọ Esau, àwọn arakunrin yín, tí wọn ń gbé òkè Seiri. Ẹ̀rù yín yóo máa bà wọ́n, nítorí náà, ẹ ṣọ́ra gidigidi; ẹ má bá wọn jà, nítorí n kò ní fun yín ní ilẹ̀ wọn, bí ó ti wù kí ó kéré tó. Mo ti fi gbogbo ilẹ̀ Edomu ní òkè Seiri fún arọmọdọmọ Esau, gẹ́gẹ́ bí ìní wọn. Ẹ óo ra oúnjẹ jẹ lọ́wọ́ wọn, ẹ óo sì ra omi mu lọ́wọ́ wọn.’ “Ẹ ranti bí OLUWA Ọlọrun yín ti bukun yín ninu gbogbo ohun tí ẹ dáwọ́lé, ó sì ti tọ́jú yín ní gbogbo ìgbà tí ẹ̀ ń rìn kiri ninu aṣálẹ̀ ńláńlá yìí. Ó ti wà pẹlu yín láti ogoji ọdún sẹ́yìn wá, ohunkohun kò sì jẹ yín níyà. “A bá kọjá lọ láàrin àwọn arakunrin wa, àwọn ọmọ Esau tí wọn ń gbé òkè Seiri, a ya ọ̀nà tí ó lọ láti Elati ati Esiongeberi sí Araba sílẹ̀. A yipada a sì gba ọ̀nà aṣálẹ̀ Moabu. OLUWA sọ fún mi pé, ‘Ẹ kò gbọdọ̀ da àwọn ará Moabu láàmú, tabi kí ẹ gbógun tì wọ́n; nítorí pé n kò fun yín ní ilẹ̀ wọn, nítorí pé mo ti fi ilẹ̀ Ari fún àwọn ọmọ Lọti gẹ́gẹ́ bí ohun ìní wọn.’ ” (Ìran àwọn òmìrán kan tí à ń pè ní Emimu ní ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí. Wọ́n pọ̀, wọ́n sì lágbára. Wọ́n ṣígbọnlẹ̀ bí àwọn ọmọ Anaki. Wọn a máa pè wọ́n ní Refaimu gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Anakimu, ṣugbọn àwọn ará Moabu ń pè wọ́n ní Emimu. Àwọn ará Hori ni wọ́n ń gbé òkè Seiri tẹ́lẹ̀ rí, ṣugbọn àwọn ọmọ Esau ti gba ilẹ̀ náà lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì ti pa wọ́n run. Wọ́n bá tẹ̀dó sórí ilẹ̀ àwọn ọmọ Hori gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Israẹli náà ti tẹ̀dó sórí ilẹ̀ tí wọ́n gbà, tí OLUWA fún wọn.) “Ẹ dìde nisinsinyii kí ẹ sì kọjá sí òdìkejì odò Seredi. A sì ṣí lọ sí òdìkejì odò Seredi. Lẹ́yìn ọdún mejidinlogoji gbáko tí a ti kúrò ní Kadeṣi Banea, ni a tó kọjá odò Seredi, títí tí gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n tó ogun ún jà ninu ìran náà fi run tán patapata, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti búra pé yóo rí. OLUWA dójúlé wọn nítòótọ́ títí gbogbo wọn fi parun patapata ninu ibùdó àwọn ọmọ Israẹli. “Lẹ́yìn tí gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n tó ogun-ún jà ti kú tán láàrin àwọn ọmọ Israẹli, OLUWA bá wí fún mi pé, ‘Òní ni ọjọ́ tí ẹ óo ré ààlà àwọn ará Moabu kọjá ní Ari. Nígbà tí ẹ bá súnmọ́ ilẹ̀ àwọn ọmọ Amoni, ẹ má ṣe dà wọ́n láàmú, ẹ má sì bá wọn jagun, nítorí pé n kò ní fun yín ní ilẹ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí ohun ìní, nítorí pé, àwọn ọmọ Lọti ni mo ti fún.’ ” (Ibẹ̀ ni wọ́n ń pè ní ilẹ̀ Refaimu, nítorí pé, àwọn Refaimu ni wọ́n ti ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀, ṣugbọn àwọn ará Amoni a máa pè wọ́n ní Samsumimu. Àwọn tí à ń pè ní Refaimu yìí pọ̀, wọ́n lágbára, wọ́n sì ṣígbọnlẹ̀ bí àwọn ọmọ Anaki, àwọn òmìrán. Ṣugbọn OLUWA pa wọ́n run fún àwọn ará Amoni, wọ́n gba ilẹ̀ wọn, wọ́n sì tẹ̀dó sibẹ. Gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti ṣe fún àwọn ọmọ Esau tí wọn ń gbé òkè Seiri nígbà tí ó pa àwọn ará Hori run fún wọn, tí àwọn ọmọ Esau gba ilẹ̀ wọn, tí wọ́n sì tẹ̀dó sibẹ títí di òní olónìí, ni ó ṣe fún àwọn ará Amoni. Àwọn ará Afimu ni wọ́n ti ń gbé àwọn ìletò tí wọ́n wà títí dé Gasa tẹ́lẹ̀ rí, ṣugbọn àwọn kan tí wọ́n wá láti Kafitori ni wọ́n pa wọ́n run, tí wọ́n sì tẹ̀dó sí ilẹ̀ wọn.) “Ẹ dìde, ẹ bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò yín, kí ẹ sì ré àfonífojì Anoni kọjá. Mo ti fi Sihoni, ọba Heṣiboni, ní ilẹ̀ àwọn ará Amori, le yín lọ́wọ́, àtòun ati ilẹ̀ rẹ̀. Ẹ bẹ̀rẹ̀ sí bá a jagun, kí ẹ sì máa gba ilẹ̀ rẹ̀. Láti òní lọ, n óo mú kí ẹ̀rù yín máa ba gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà láyé yìí, tí wọ́n bá gbúròó yín, wọn yóo máa gbọ̀n, ojora yóo sì mú wọn nítorí yín. “Nítorí náà mo rán àwọn oníṣẹ́ láti aṣálẹ̀ Kedemotu, sí Sihoni, ọba Heṣiboni. Iṣẹ́ alaafia ni mo rán sí i, mo ní, ‘Jẹ́ kí n kọjá láàrin ilẹ̀ rẹ. Ojú ọ̀nà tààrà ni n óo máa gbà lọ. N kò ní yà sí ọ̀tún tabi sí òsì. Rírà ni n óo ra oúnjẹ tí n óo jẹ lọ́wọ́ rẹ, n óo sì ra omi tí n óo mu pẹlu. Ṣá ti gbà mí láàyè kí n kọjá, bí àwọn ọmọ Esau, tí wọn ń gbé Seiri ati àwọn ará Moabu tí wọn ń gbé Ari, ti ṣe fún mi, títí tí n óo fi kọjá odò Jọdani, lọ sí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun wa ti fi fún wa.’ “Ṣugbọn Sihoni, ọba Heṣiboni kọ̀ fún wa, kò jẹ́ kí á kọjá lọ́dọ̀ rẹ̀; nítorí OLUWA Ọlọrun yín mú kí ọkàn rẹ̀ le, ó sì mú kí ó ṣe oríkunkun, kí ó lè fi le yín lọ́wọ́, bí ó ti ṣe lónìí. “OLUWA sọ fún mi pé, ‘Wò ó, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí fi Sihoni ati ilẹ̀ rẹ̀ le yín lọ́wọ́, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí gbà á, kí ẹ lè máa gbé ibẹ̀.’ Sihoni bá jáde sí wa, òun ati àwọn eniyan rẹ̀, láti bá wa jagun ní Jahasi. OLUWA Ọlọrun wa fi lé wa lọ́wọ́, a ṣẹgun rẹ̀, ati òun ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀. A gba àwọn ìlú ńláńlá rẹ̀ nígbà náà, a sì run wọ́n, ati ọkunrin, ati obinrin, ati àwọn ọmọ wọn. A kò dá ohunkohun sí, àfi àwọn ohun ọ̀sìn tí a kó bí ìkógun, pẹlu àwọn ìkógun tí a kó ninu àwọn ìlú tí a gbà. Láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Anoni lọ, ati ìlú ńlá tí ó wà ní àfonífojì, títí dé Gileadi, kò sí ìlú tí ó ju agbára wa lọ. OLUWA Ọlọrun wa fi gbogbo wọn lé wa lọ́wọ́, àfi ilẹ̀ àwọn ọmọ Amoni nìkan ni ẹ kò súnmọ́, àwọn ilẹ̀ tí ó wà ní etí odò Jaboku, ati àwọn ìlú ńláńlá tí ó wà ní agbègbè olókè, ati gbogbo ibi tí OLUWA Ọlọrun wa ti paláṣẹ pé a kò gbọdọ̀ dé. “Lẹ́yìn náà, a gbéra, a doríkọ ọ̀nà Baṣani. Ogu, ọba Baṣani, ati àwọn eniyan rẹ̀ bá ṣígun wá pàdé wa ní Edirei. Ṣugbọn OLUWA wí fún mi pé, ‘Má bẹ̀rù rẹ̀, nítorí pé mo ti fi òun ati àwọn eniyan rẹ̀ ati ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́, ohun tí o ṣe sí Sihoni, ọba àwọn ará Amori, tí ń gbé Heṣiboni ni kí o ṣe sí òun náà.’ “OLUWA Ọlọrun wa bá fi Ogu, ọba Baṣani, lé wa lọ́wọ́, ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀. A pa wọ́n títí tí kò fi ku ẹnikẹ́ni ninu àwọn eniyan rẹ̀. A gba gbogbo àwọn ìlú ńláńlá rẹ̀ nígbà náà, kò sí ìlú kan tí a kò gbà lọ́wọ́ wọn ninu gbogbo àwọn ìlú wọn. Gbogbo ìlú wọn jẹ́ ọgọta, gbogbo agbègbè Arigobu ati ìjọba Ogu ní Baṣani ni a gbà. Wọ́n mọ odi gíga gíga yípo gbogbo àwọn ìlú ọ̀hún, olukuluku wọ́n sì ní odi tí ó ga ati ẹnubodè pẹlu ọ̀pá ìdábùú, láìka ọpọlọpọ àwọn ìlú kéékèèké tí kò ní odi. A run gbogbo wọn patapata gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe sí Sihoni, ọba Heṣiboni, tí a run gbogbo àwọn ìlú rẹ̀, ati ọkunrin, ati obinrin, ati ọmọde. Ṣugbọn a kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, ati àwọn ohun tí a rí ninu ìlú wọn bí ìkógun. “A gba ilẹ̀ náà lọ́wọ́ àwọn ọba Amori mejeeji tí wọ́n wà ní òkè odò Jọdani nígbà náà. Ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ láti àfonífojì Anoni títí dé òkè Herimoni. (Herimoni Sirioni ni àwọn ará Sidoni ń pe òkè náà, ṣugbọn àwọn ará Amori ń pè é ní Seniri.) A sì tún gba gbogbo àwọn ìlú wọn tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, gbogbo ilẹ̀ Gileadi ati gbogbo ilẹ̀ Baṣani títí dé Saleka ati Edirei, àwọn ìlú tí ó wà ninu ìjọba Ogu, ọba Baṣani.” (Nítorí pé, Ogu, ọba Baṣani nìkan ni ó kù ninu ìran àwọn Refaimu. Irin ni wọ́n fi ṣe pósí rẹ̀, ó sì wà ní Raba, ní ilẹ̀ àwọn Amoni títí di òní olónìí. Igbọnwọ mẹsan-an ni gígùn pósí náà, ó sì fẹ̀ ní igbọnwọ mẹrin. Igbọnwọ tí ó péye ni wọ́n fi ṣe ìdíwọ̀n pósí náà.) “Nígbà tí a gba ilẹ̀ náà nígbà náà, àwọn ọmọ Reubẹni ati àwọn ọmọ Gadi ni mo fún, ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Anoni ati ìdajì agbègbè olókè ti Gileadi, pẹlu gbogbo àwọn ìlú ńláńlá rẹ̀. Ìdajì tí ó kù lára ilẹ̀ àwọn ará Gileadi, ati gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Baṣani tíí ṣe ìjọba Ogu, ati gbogbo agbègbè Arigobu, ni mo fún ìdajì ẹ̀yà Manase.” (Gbogbo ilẹ̀ Baṣani ni wọ́n ń pè ní ilẹ̀ àwọn Refaimu. Jairi láti inú ẹ̀yà Manase ni ó gba gbogbo agbègbè Arigobu tí à ń pè ní Baṣani, títí dé etí ààlà ilẹ̀ àwọn Geṣuri, ati ti àwọn Maakati. Ó sọ àwọn ìlú náà ní orúkọ ara rẹ̀; ó pè wọ́n ní Hafoti Jairi. Orúkọ náà ni wọ́n ń jẹ́ títí di òní olónìí.) Makiri, láti inú ẹ̀yà Manase ni mo fún ní ilẹ̀ Gileadi. Àwọn ọmọ Reubẹni ati àwọn ọmọ Gadi ni mo sì fún ní agbègbè Gileadi títí dé àfonífojì Anoni, ààrin gbùngbùn àfonífojì náà ni ààlà ilẹ̀ wọn, títí lọ kan odò Jaboku, tíí ṣe ààlà àwọn ará Amoni; ati ilẹ̀ Araba títí kan odò Jọdani. Láti Kinereti títí dé Òkun Araba tí wọn ń pè ní Òkun Iyọ̀, ní ẹsẹ̀ òkè Pisiga ní apá ìlà oòrùn. “Mo pàṣẹ fun yín nígbà náà, mo ní, ‘OLUWA Ọlọrun yín ti fi ilẹ̀ yìí fun yín bíi ohun ìní; gbogbo àwọn akọni ninu àwọn ọkunrin yín yóo kọjá lọ pẹlu ihamọra ogun ṣiwaju àwọn ọmọ Israẹli, arakunrin yín. Ṣugbọn àwọn aya yín ati àwọn ọmọ yín kéékèèké ati àwọn ẹran ọ̀sìn yín (mo mọ̀ pé wọ́n ti di pupọ nisinsinyii) yóo wà ninu àwọn ìlú tí mo ti fun yín títí tí OLUWA yóo fi fún àwọn arakunrin yín ní ìsinmi bí ó ti fún yín, tí àwọn náà yóo wà lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun wọn ní òdìkejì odò Jọdani. Nígbà náà ni olukuluku yín yóo to pada sórí ilẹ̀ tí mo ti fun yín.’ “Mo sọ fún Joṣua nígbà náà pé; ‘Ṣé ìwọ náà ti fi ojú ara rẹ rí ohun tí OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe sí àwọn ọba meji wọnyi? Bẹ́ẹ̀ gan-an ni OLUWA yóo ṣe sí ìjọba yòókù tí ẹ óo gbà. Ẹ kò gbọdọ̀ bẹ̀rù wọn rárá, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín ni ó ń jà fun yín.’ “Mo bẹ OLUWA nígbà náà, mo ní, ‘OLUWA Ọlọrun, o ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fi títóbi ati agbára rẹ han èmi iranṣẹ rẹ ni; nítorí pé, oriṣa wo ló wà, lọ́run tabi láyé yìí tí ó lè ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu bíi tìrẹ? Mo bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí n kọjá sí òdìkejì Jọdani kí n sì rí ilẹ̀ dáradára náà, agbègbè olókè dáradára nnì ati Lẹbanoni.’ “Ṣugbọn OLUWA bínú sí mi nítorí yín, kò sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi. OLUWA dá mi lóhùn, ó ní, ‘Ó tó gẹ́ẹ́, má ṣe bá mi sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ mọ́. Gun orí òkè Pisiga lọ, gbé ojú sókè, kí o sì wo apá ìwọ̀ oòrùn, ati apá àríwá, ati apá gúsù, ati apá ìlà oòrùn. Ojú ni o óo fi rí i, nítorí pé, o kò ní kọjá odò Jọdani yìí sí òdìkejì. Ṣugbọn pàṣẹ fún Joṣua, mú un lọ́kàn le, kí o sì kì í láyà; nítorí pé, òun ni yóo ṣiwaju àwọn eniyan wọnyi lọ, tí wọn yóo fi gba ilẹ̀ tí o óo rí.’ “Nítorí náà a bá dúró sí àfonífojì, ní òdìkejì Betipeori.” Mose wí fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ fi ọkàn sí àwọn ìlànà ati òfin tí mò ń kọ yín yìí, kí ẹ máa tẹ̀lé wọn, kí ẹ lè wà láàyè, kí ẹ lè dé ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín ń mu yín lọ, kí ẹ sì lè gbà á. Ẹ kò gbọdọ̀ fi kún òfin tí mo fun yín yìí, ẹ kò sì gbọdọ̀ mú kúrò ninu rẹ̀, kí ẹ lè máa pa òfin OLUWA Ọlọrun yín tí mo fun yín mọ́. Ẹ̀yin náà ti fi ojú yín rí ohun tí OLUWA ṣe ní Baali Peori, nítorí pé, OLUWA Ọlọrun yín pa gbogbo àwọn tí wọn ń bọ oriṣa Baali tí ó wà ní Peori run kúrò láàrin yín. Ṣugbọn gbogbo ẹ̀yin tí ẹ di OLUWA Ọlọrun yín mú ṣinṣin ni ẹ wà láàyè títí di òní. “Mo ti kọ yín ní ìlànà ati òfin gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun ti pa á láṣẹ fún mi, kí ẹ lè máa tẹ̀lé wọn nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà. Ẹ máa pa wọ́n mọ́, kí ẹ sì máa tẹ̀lé wọn, wọn yóo sì sọ yín di ọlọ́gbọ́n ati olóye lójú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Orílẹ̀-èdè tí ó bá gbọ́ nípa àwọn ìlànà ati òfin wọnyi yóo wí pé, dájúdájú ọlọ́gbọ́n ati amòye eniyan ni yín. “Ǹjẹ́, orílẹ̀-èdè ńlá wo ni ó tún wà, tí ó ní oriṣa tí ó súnmọ́ ọn gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun tií súnmọ́ wa nígbàkúùgbà tí a bá pè é? Tabi orílẹ̀-èdè ńlá wo ni ó tún wà, tí ó ní ìlànà ati òfin òdodo gẹ́gẹ́ bí àwọn tí mo gbé ka iwájú yín lónìí? Ẹ ṣọ́ra gidigidi, kí ẹ sì ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, kí ẹ má baà gbàgbé àwọn ohun tí ẹ ti fi ojú ara yín rí, kí iyè yín má baà fò wọ́n ní gbogbo ọjọ́ ayé yín. Ẹ máa pa á nítàn fún àwọn ọmọ yín ati àwọn ọmọ ọmọ yín, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti dúró níwájú OLUWA Ọlọrun yín lẹ́bàá òkè Sinai, tí ó fi sọ fún mi pé, ‘Pe àwọn eniyan náà jọ sọ́dọ̀ mi, kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí wọ́n lè kọ́ láti máa bẹ̀rù mi ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn; kí wọ́n sì kọ́ àwọn ọmọ wọn pẹlu.’ “Lẹ́yìn náà, ẹ súnmọ́ òkè náà, nígbà tí ó ń jóná, tóbẹ́ẹ̀ tí ahọ́n iná náà fẹ́rẹ̀ kan ojú ọ̀run, tí òkùnkùn ati ìkùukùu bo òkè náà. Ọlọrun ba yín sọ̀rọ̀ láti inú iná náà wá, ẹ gbọ́ ohùn rẹ̀, ṣugbọn ẹ kò rí i. Ohùn rẹ̀ nìkan ni ẹ̀ ń gbọ́. Ó sọ majẹmu rẹ̀ fun yín, tíí ṣe àwọn òfin mẹ́wàá tí ó pa láṣẹ fun yín láti tẹ̀lé, ó sì kọ wọ́n sí orí tabili òkúta meji. OLUWA pàṣẹ fún mi nígbà náà, láti kọ yín ní ìlànà ati òfin rẹ̀, kí ẹ lè máa tẹ̀lé wọn ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà. “Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra gidigidi, níwọ̀n ìgbà tí ẹ kò rí ìrísí OLUWA ní ọjọ́ tí ó ba yín sọ̀rọ̀ láàrin iná ní Horebu, ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà dẹ́ṣẹ̀ nípa yíyá ère fún ara yín, irú ère yòówù tí ó lè jẹ́; kì báà ṣe akọ tabi abo, yálà àwòrán ẹrankokẹ́ranko tí ó wà ní orílẹ̀ ayé, tabi àwòrán ẹyẹkẹ́yẹ tí ń fò lójú ọ̀run, kì báà ṣe àwòrán ohunkohun tí ń rìn lórí ilẹ̀, tabi àwòrán ẹjakẹ́ja tí ń bẹ ninu omi. Ẹ ṣọ́ra nígbà tí ẹ bá gbé ojú yín sókè sí ojú ọ̀run, tí ẹ bá rí oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀, ati ogunlọ́gọ̀ àwọn ohun tí ó wà ní ojú ọ̀run, kí ọkàn yín má baà fà sí wọn, kí ẹ sì máa bọ àwọn ohun tí OLUWA Ọlọrun yín fún gbogbo eniyan láyé. Ọlọrun ti yọ yín kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, ilẹ̀ tí ó dàbí iná ìléru ńlá, ó ko yín jáde láti jẹ́ eniyan rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti jẹ́ lónìí. Nítorí tiyín gan-an ni OLUWA ṣe bínú sí mi, tí ó sì fi ibinu búra pé, n kò ní kọjá sí òdìkejì Jọdani, n kò sì ní dé ilẹ̀ dáradára náà, tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín. Nítorí náà, mo níláti kú ní ìhín yìí, n kò gbọdọ̀ rékọjá sí òdìkejì Jọdani, ṣugbọn ẹ̀yin óo rékọjá sí òdìkejì rẹ̀, ẹ óo sì gba ilẹ̀ dáradára náà. Ẹ ṣọ́ra gidigidi, ẹ má gbàgbé majẹmu tí OLUWA Ọlọrun yín ba yín dá, ẹ má sì yá èrekére fún ara yín, ní àwòrán ohunkohun, nítorí pé, OLUWA Ọlọrun yín lòdì sí i. Nítorí iná tí ń jó ni run ni OLUWA Ọlọrun yín, Ọlọrun tíí máa ń jowú sì ni. “Nígbà tí ẹ bá ní ọmọ, ati àwọn ọmọ ọmọ, tí ẹ ti pẹ́ ní ilẹ̀ náà; bí ẹ bá dẹ́ṣẹ̀, nípa yíyá ère ní àwòrán ohunkohun, ati nípa ṣíṣe ohun tí ó burú níwájú OLUWA, tí ó lè mú un bínú, ọ̀run ati ayé ń gbọ́ bí mo ti ń sọ yìí, pé ẹ óo parun patapata lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń rékọjá lọ gbà ní òdìkejì Jọdani. Ẹ kò ní pẹ́ níbẹ̀ rárá, ṣugbọn píparun ni ẹ óo parun. OLUWA yóo fọn yín káàkiri sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn tí wọn yóo sì ṣẹ́kù ninu yín kò ní tó nǹkan láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA yóo fọn yín ká sí. Ẹ óo sì máa bọ oriṣa tí a fi igi ati òkúta gbẹ́ níbẹ̀. Iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni àwọn oriṣa wọnyi; wọn kò lè gbọ́ràn, tabi kí wọn ríran; wọn kò lè jẹun, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè gbóòórùn. Níbẹ̀ ni ẹ óo ti wá OLUWA Ọlọrun yín tí ẹ óo sì rí i, tí ẹ bá wá a tọkàntọkàn pẹlu gbogbo ẹ̀mí yín. Nígbà tí ẹ bá wà ninu ìpọ́njú, tí gbogbo nǹkan wọnyi bá ń ṣẹlẹ̀ sí yín lọ́jọ́ iwájú, ẹ óo pada sí ọ̀dọ̀ OLUWA Ọlọrun yín, ẹ óo sì gbọ́ tirẹ̀. Nítorí pé, aláàánú ni OLUWA Ọlọrun yín, kò ní já yín kulẹ̀, kò ní pa yín run, bẹ́ẹ̀ ni kò ní gbàgbé majẹmu tí ó fi ìbúra bá àwọn baba ńlá yín dá. “Ẹ lọ wádìí wò bí ó bá ṣẹlẹ̀ rí kí wọ́n tó bí yín, láti ọjọ́ tí Ọlọrun ti dá eniyan, ẹ wádìí káàkiri jákèjádò gbogbo àgbáyé bóyá irú nǹkan ńlá báyìí ṣẹlẹ̀ rí, tabi wọ́n pa á nítàn rí. Ǹjẹ́ orílẹ̀-èdè kan gbọ́ kí oriṣa kan sọ̀rọ̀ láti ààrin gbùngbùn iná rí, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gbọ́, tí ẹ sì tún wà láàyè? Tabi pé, oriṣa kan ti dìde rí, tí ó gbìdánwò àtifi ipá gba orílẹ̀-èdè kan fún ara rẹ̀ lọ́wọ́ orílẹ̀-èdè mìíràn, pẹlu àmì rẹ̀, ati iṣẹ́ ìyanu, ati ogun, ati agbára ati àwọn nǹkan tí ó bani lẹ́rù, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fi ojú yín rí i tí OLUWA Ọlọrun yín ṣe fun yín ní Ijipti? OLUWA fi èyí hàn yín, kí ẹ lè mọ̀ pé òun ni Ọlọrun, ati pé kò sí Ọlọrun mìíràn àfi òun nìkan. Ó mú kí ẹ gbọ́ ohùn rẹ̀ láti ọ̀run wá, kí ó lè kọ yín; ó sì mú kí ẹ rí iná ńlá rẹ̀ láyé, ẹ sì gbọ́ ohùn rẹ̀ láàrin iná náà. Ìdí tí ó fi ṣe èyí ni pé, ó fẹ́ràn àwọn baba ńlá yín, ó sì yan ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ ọmọ ọmọ wọn; ó fi agbára ko yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, ó sì wà pẹlu yín. Ó lé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n pọ̀ jù yín lọ, tí wọ́n sì lágbára jù yín lọ kúrò fun yín, kí ó baà lè ko yín wọlé kí ó sì fun yín ní ilẹ̀ wọn, kí ẹ sì jogún rẹ̀ bí ó ti wà lónìí. Kí ẹ mọ̀ lónìí, kí ó sì da yín lójú pé, OLUWA ni Ọlọrun; kò sí ọlọrun mìíràn mọ́ ní ọ̀run ati ní ayé. Nítorí náà, ẹ máa pa àwọn ìlànà ati òfin rẹ̀ tí mo fun yín lónìí mọ́, kí ó lè dára fun yín, ati fún àwọn ọmọ yín; kí ẹ lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, títí lae.” Mose ya ìlú mẹta sọ́tọ̀ ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani, gẹ́gẹ́ bí ìlú ààbò, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá paniyan lè máa sálọ sibẹ; kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì pa aládùúgbò rẹ̀, láìjẹ́ pé wọ́n ní ìkùnsínú sí ara wọn tẹ́lẹ̀, lè sálọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú wọnyi, kí ó lè gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là. Ó ya Beseri sọ́tọ̀ fún ẹ̀yà Reubẹni ninu aṣálẹ̀ láàrin ilẹ̀ tí ó tẹ́jú. Ó ya Ramoti sọ́tọ̀ ní Gileadi, fún ẹ̀yà Gadi, ó sì ya Golani sọ́tọ̀ ní Baṣani, fún ẹ̀yà Manase. Mose fún àwọn ọmọ Israẹli ní àwọn òfin; ó sì fi àwọn ìlànà ati àṣẹ lélẹ̀ fún wọn nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Ijipti, nígbà tí wọ́n dé òdìkejì odò Jọdani, ní àfonífojì tí ó dojú kọ Betipeori, ní ilẹ̀ Sihoni, ọba àwọn ará Amori tí ń gbé Heṣiboni. Mose ati àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun Sihoni nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Ijipti. Wọ́n gba ilẹ̀ rẹ̀ ati ilẹ̀ Ogu, ọba Baṣani, Sihoni ati Ogu ni ọba àwọn ará Amori tí wọn ń gbé òdìkejì odò Jọdani ní apá ìlà oòrùn láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Anoni títí dé òkè Sirioni (tí à ń pè ní òkè Herimoni), ati gbogbo agbègbè Araba ní apá ìlà oòrùn odò Jọdani títí dé Òkun Araba, tí à ń pè ní Òkun Iyọ̀, tí ó wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Pisiga. Mose pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ gbọ́ àwọn ìlànà ati àwọn òfin tí n óo kà fun yín lónìí; ẹ kọ́ wọn, kí ẹ sì rí i pé ẹ̀ ń tẹ̀lé wọn. OLUWA Ọlọrun wa bá wa dá majẹmu kan ní òkè Horebu. Kì í ṣe àwọn baba wa ni OLUWA bá dá majẹmu yìí, ṣugbọn àwa gan-an tí a wà láàyè níhìn-ín lónìí ni ó bá dá majẹmu náà. OLUWA bá yín sọ̀rọ̀ lojukooju lórí òkè ní ààrin iná. Èmi ni mo dúró láàrin ẹ̀yin ati OLUWA nígbà náà, tí mo sì sọ ohun tí OLUWA wí fun yín; nítorí ẹ̀rù iná náà ń bà yín, ẹ kò sì gun òkè náà lọ. “OLUWA ní, ‘Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó ko yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, ní oko ẹrú tí ẹ wà: “ ‘O kò gbọdọ̀ bọ oriṣa, èmi OLUWA ni kí o máa sìn. “ ‘O kò gbọdọ̀ yá èrekére kankan fún ara rẹ, kì báà jẹ́ ní àwòrán ohunkohun tí ó wà ní ojú ọ̀run tabi ti ohun tí ó wà lórí ilẹ̀, tabi èyí tí ó wà ninu omi ní abẹ́ ilẹ̀. O kò gbọdọ̀ tẹríba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ sìn wọ́n, nítorí pé Ọlọrun tíí máa ń jowú ni èmi OLUWA Ọlọrun rẹ. Èmi a máa fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ ati ọmọ ọmọ, títí dé ìran kẹta ati ìran kẹrin ninu àwọn tí wọ́n kórìíra mi. Ṣugbọn èmi a máa fi ìfẹ́ mi, tí kì í yẹ̀, hàn sí ẹgbẹẹgbẹrun àwọn tí wọ́n fẹ́ràn mi, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé òfin mi. “ ‘O kò gbọdọ̀ pe orúkọ OLUWA Ọlọrun rẹ lásán; nítorí pé, èmi OLUWA yóo dá ẹnikẹ́ni tí ó bá pe orúkọ mi lásán lẹ́bi. “ ‘Ya ọjọ́ ìsinmi sọ́tọ̀, kí o sì ṣe é ní ọjọ́ mímọ́, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun rẹ ti pàṣẹ fún ọ. Ọjọ́ mẹfa ni kí o fi ṣe gbogbo làálàá ati iṣẹ́ rẹ; ṣugbọn ọjọ́ keje jẹ́ ọjọ́ ìsinmi fún OLUWA Ọlọrun rẹ. Ní ọjọ́ náà, o kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan, ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ọkunrin, ati àwọn ọmọ rẹ obinrin, ati àwọn iranṣẹkunrin rẹ, ati àwọn iranṣẹbinrin rẹ, ati mààlúù rẹ, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ, ati àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ, ati àlejò tí ń gbé ilẹ̀ rẹ; kí iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin rẹ lè sinmi bí ìwọ náà ti sinmi. Ranti pé, ìwọ pàápàá ti jẹ́ ẹrú ní ilẹ̀ Ijipti rí, ati pé OLUWA Ọlọrun rẹ ni ó fi agbára rẹ̀ mú ọ jáde. Nítorí náà ni OLUWA Ọlọrun rẹ fi pa á láṣẹ fún ọ láti ya ọjọ́ ìsinmi sọ́tọ̀. “ ‘Bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun rẹ ti pa á láṣẹ fún ọ; kí o lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun rẹ fún ọ, kí ó sì lè máa dára fún ọ. “ ‘O kò gbọdọ̀ paniyan. “ ‘O kò gbọdọ̀ ṣe panṣaga. “ ‘O kò gbọdọ̀ jalè. “ ‘O kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké sí aládùúgbò rẹ. “ ‘O kò gbọdọ̀ ṣe ojú kòkòrò sí aya ẹlòmíràn, tabi ilé rẹ̀, tabi oko rẹ̀, tabi iranṣẹkunrin rẹ̀, tabi iranṣẹbinrin rẹ̀, tabi akọ mààlúù rẹ̀, tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, tabi ohunkohun tíí ṣe ti ẹlòmíràn.’ “Àwọn òfin tí OLUWA fún gbogbo yín nìyí, nígbà tí ẹ fi péjọ lẹ́sẹ̀ òkè, tí ó fi fi ohùn rara ba yín sọ̀rọ̀ láti inú iná ati ìkùukùu, ati òkùnkùn biribiri. Àwọn òfin yìí nìkan ni ó fun yín, kò sí òmíràn lẹ́yìn wọn, ó kọ wọ́n sára tabili òkúta meji, ó sì kó wọn fún mi. “Nígbà tí ẹ gbọ́ ohùn láti inú òkùnkùn biribiri, tí iná sì ń jó lórí òkè, gbogbo àwọn olórí ẹ̀yà yín ati àwọn àgbààgbà wá sọ́dọ̀ mi; wọ́n ní, ‘OLUWA Ọlọrun wa ti fi títóbi ati ògo rẹ̀ hàn wá, a sì ti gbọ́ ohùn rẹ̀ láàrin iná. Lónìí ni a rí i tí Ọlọrun bá eniyan sọ̀rọ̀, tí olúwarẹ̀ sì tún wà láàyè. Nítorí náà, kí ló dé tí a óo fi kú? Nítorí pé, iná ńlá yìí yóo jó wa run; bí a bá tún gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun wa sí i, a óo kú. Nítorí pé ninu gbogbo ẹ̀dá alààyè, ta ni ó tíì gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun alààyè rí láti inú iná, gẹ́gẹ́ bí àwa ti gbọ́ ọ yìí, tí ó sì wà láàyè? Ìwọ Mose, súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, kí o sì gbọ́ gbogbo ohun tí OLUWA Ọlọrun yóo sọ, kí o wá sọ fún wa, a óo sì ṣe é.’ “OLUWA gbọ́ ọ̀rọ̀ yín nígbà tí ẹ̀ ń bá mi sọ̀rọ̀, ó sì wí fún mi pé, ‘Mo gbọ́ ohun tí àwọn eniyan wọnyi bá ọ sọ; gbogbo ohun tí wọ́n sọ pátá ni ó dára. Yóo ti dára tó, bí wọ́n bá ní irú ẹ̀mí yìí nígbà gbogbo, kí wọ́n bẹ̀rù mi, kí wọ́n sì pa gbogbo òfin mi mọ́, kí ó lè dára fún wọn, ati fún àwọn ọmọ wọn títí lae. Lọ sọ fún wọn pé, kí wọ́n pada sinu àgọ́ wọn. Ṣugbọn ìwọ dúró tì mí níhìn-ín, n óo sì sọ gbogbo òfin ati ìlànà ati ìdájọ́ tí o óo kọ́ wọn, kí wọ́n lè máa pa wọ́n mọ́, ní ilẹ̀ tí n óo fún wọn.’ “Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra kí ẹ sì ṣe gbogbo ohun tí OLUWA Ọlọrun yín pa láṣẹ fun yín; ẹ kò gbọdọ̀ ṣe àìgbọràn ninu ohunkohun. Gbogbo ọ̀nà tí OLUWA Ọlọrun yín là sílẹ̀ ni kí ẹ máa tọ̀, kí ẹ lè wà láàyè, kí ó lè dára fun yín, kí ẹ sì lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ óo gbà. “Àwọn òfin ati ìlànà, ati ìdájọ́ tí OLUWA Ọlọrun yín pa láṣẹ fún mi láti fi kọ yín nìwọ̀nyí; kí ẹ lè máa tẹ̀lé wọn ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà; kí ẹ lè máa bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín, ẹ̀yin ati arọmọdọmọ yín, kí ẹ lè máa tẹ̀lé àwọn ìlànà ati òfin tí mo fun yín lónìí, ní gbogbo ọjọ́ ayé yín, kí ẹ lè pẹ́ láyé. Ẹ gbọ́ nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ máa tẹ̀lé àwọn òfin náà, kí ó lè dára fun yín, kí ẹ sì lè pọ̀ sí i, ní ilẹ̀ tí ó dára, tí ó kún fún wàrà ati oyin, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín ti ṣe ìlérí fun yín. “Ẹ gbọ́ Israẹli: OLUWA Ọlọrun yín, OLUWA kan ṣoṣo ni. Ẹ gbọdọ̀ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín pẹlu gbogbo ọkàn yín, ati gbogbo ẹ̀mí yín, ati gbogbo agbára yín. Ẹ fi àṣẹ tí mo pa fun yín lónìí sọ́kàn, kí ẹ sì fi kọ́ àwọn ọmọ yín dáradára. Ẹ máa fi wọ́n ṣe ọ̀rọ̀ sọ nígbà tí ẹ bá jókòó ninu ilé yín, ati nígbà tí ẹ bá ń rìn lọ lójú ọ̀nà, ati nígbà tí ẹ bá dùbúlẹ̀, ati nígbà tí ẹ bá dìde. Ẹ so wọ́n mọ́ ọwọ́ yín gẹ́gẹ́ bí àmì, kí ẹ fi ṣe ọ̀já ìgbàjú, kí ó wà ní agbede meji ojú yín. Ẹ kọ wọ́n sí ara òpó ìlẹ̀kùn ilé yín, ati sí ara ẹnu ọ̀nà ìta ilé yín. “Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá mu yín wọ ilẹ̀ tí ó búra fún Abrahamu, ati Isaaki, ati Jakọbu, àwọn baba yín, pé òun yóo fun yín, ilẹ̀ tí ó kún fún àwọn ìlú ńláńlá tí wọ́n dára, tí kìí ṣe ẹ̀yin ni ẹ tẹ̀ wọ́n dó, ati àwọn ilé tí ó kún fún àwọn nǹkan dáradára, tí kìí ṣe ẹ̀yin ni ẹ kó wọn sibẹ, ati kànga omi, tí kìí ṣe ẹ̀yin ni ẹ gbẹ́ ẹ, ati àwọn ọgbà àjàrà ati igi olifi tí kìí ṣe ẹ̀yin ni ẹ gbìn ín. Nígbà tí ẹ bá jẹ, tí ẹ yó tán, ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà gbàgbé OLUWA tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, níbi tí ẹ ti jẹ́ ẹrú. Ẹ gbọdọ̀ bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín, kí ẹ sì máa sìn ín. Orúkọ rẹ̀ ni kí ẹ máa fi búra. Ẹ kò gbọdọ̀ bọ èyíkéyìí ninu àwọn oriṣa tí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà ní àyíká yín ń bọ, nítorí pé, OLUWA Ọlọrun yín tí ó wà láàrin yín, Ọlọrun tíí máa ń jowú ni; kí inú má baà bí OLUWA Ọlọrun yín sí yín, kí ó sì pa yín run kúrò lórí ilẹ̀ ayé. “Ẹ kò gbọdọ̀ dán OLUWA Ọlọrun yín wò, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ní Masa. Ẹ gbọdọ̀ pa àwọn òfin OLUWA Ọlọrun yín mọ́ dáradára, kí ẹ sì máa tẹ̀lé àwọn òfin ati àwọn ìlànà rẹ̀, tí ó fi lélẹ̀ fun yín. Ẹ gbọdọ̀ máa ṣe ohun tí ó tọ́, ati ohun tí ó yẹ lójú OLUWA; kí ó lè dára fun yín, kí ẹ lè lọ gba ilẹ̀ dáradára tí OLUWA ti búra láti fún àwọn baba yín, kí OLUWA lè lé àwọn ọ̀tá yín jáde fun yín, bí ó ti ṣèlérí. “Nígbà tí àwọn ọmọ yín bá bèèrè lọ́jọ́ iwájú pé, kí ni ìtumọ̀ àwọn ẹ̀rí ati ìlànà ati òfin tí OLUWA pa láṣẹ fun yín. Ẹ óo dá wọn lóhùn pé, ‘A ti jẹ́ ẹrú Farao ní ilẹ̀ Ijipti rí, ṣugbọn agbára ni OLUWA fi kó wa jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. Àwa pàápàá fi ojú wa rí i bí OLUWA ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá tí wọ́n bani lẹ́rù sí àwọn ará Ijipti ati sí Farao ọba wọn, ati gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀. OLUWA sì kó wa jáde, kí ó lè kó wa wá sí orí ilẹ̀ tí ó ti búra láti fi fún àwọn baba wa. OLUWA pa á láṣẹ fún wa pé kí á máa tẹ̀lé gbogbo àwọn ìlànà wọnyi, kí á bẹ̀rù òun OLUWA Ọlọrun wa fún ire ara wa nígbà gbogbo, kí ó lè dá wa sí, kí á sì wà láàyè bí a ti wà lónìí yìí. A óo kà wá sí olódodo bí a bá pa gbogbo àwọn òfin wọnyi mọ́ níwájú OLUWA Ọlọrun wa, bí ó ti pa á láṣẹ fún wa.’ “Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá ko yín wọ ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ yìí, tí ẹ bá gba ilẹ̀ náà, tí OLUWA sì lé ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè jáde fun yín, àwọn orílẹ̀-èdè bíi Hiti, Girigaṣi, Amori, Kenaani, Perisi, Hifi, Jebusi, àní àwọn orílẹ̀-èdè meje tí wọ́n tóbi jù yín lọ, tí wọ́n sì lágbára jù yín lọ; nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá fi wọ́n le yín lọ́wọ́, tí ẹ bá sì ṣẹgun wọn, píparun ni ẹ gbọdọ̀ pa wọ́n run. Ẹ kò gbọdọ̀ bá wọn dá majẹmu, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣàánú fún wọn rárá. Ẹ kò gbọdọ̀ fi ọmọ yín fún àwọn ọmọkunrin wọn láti fẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ fẹ́ ọmọ wọn fún àwọn ọmọkunrin yín. Nítorí pé, wọn óo yí àwọn ọmọ yín lọ́kàn pada, wọn kò ní jẹ́ kí wọ́n tẹ̀lé èmi OLUWA mọ́. Àwọn oriṣa ni wọn óo máa bọ, èmi OLUWA yóo bínú si yín nígbà náà, n óo sì pa yín run kíákíá. Ohun tí ẹ óo ṣe sí wọn nìyí: ẹ wó gbogbo pẹpẹ wọn lulẹ̀, ẹ rún àwọn òpó wọn, ẹ gé àwọn oriṣa Aṣera wọn lulẹ̀, kí ẹ sì sun gbogbo àwọn ère wọn níná. Nítorí pé, ẹni mímọ́ ni ẹ jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun yín, OLUWA Ọlọrun yín ti yàn yín, láàrin gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ní gbogbo ayé, pé kí ẹ jẹ́ ohun ìní fún òun. “Kì í ṣe pé ẹ pọ̀ ju àwọn eniyan yòókù lọ ni OLUWA fi fẹ́ràn yín, tí ó sì fi yàn yín. Ninu gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹ̀yin ni ẹ kéré jùlọ. Ṣugbọn, nítorí pé OLUWA fẹ́ràn yín, ati nítorí ìbúra tí ó ti ṣe fún àwọn baba yín, ni ó ṣe fi agbára ko yín jáde, tí ó sì rà yín pada kúrò ní oko ẹrú, lọ́wọ́ Farao, ọba Ijipti. Nítorí náà, ẹ máa ranti pé OLUWA Ọlọrun yín ni Ọlọrun, Ọlọrun olótìítọ́ tíí pa majẹmu mọ́, tíí sì ń fi ìfẹ́ ńlá rẹ̀ hàn sí àwọn tí wọ́n bá fẹ́ ẹ, tí wọ́n sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́, títí dé ẹgbẹrun ìran, a sì máa san ẹ̀san lojukooju fún àwọn tí wọ́n kórìíra rẹ̀. Yóo pa wọ́n run, kò ní dáwọ́ dúró láti má gba ẹ̀san lára gbogbo àwọn tí wọ́n kórìíra rẹ̀, yóo san ẹ̀san fún wọn ní ojúkoojú. Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ ṣọ́ra kí ẹ sì máa pa òfin rẹ̀ mọ́, kí ẹ sì tẹ̀lé ìlànà ati ìdájọ́ rẹ̀ tí mo fun yín lónìí. “Bi ẹ bá fetí sí òfin wọnyi, tí ẹ sì pa wọ́n mọ́, OLUWA Ọlọrun yín yóo mú majẹmu tí ó bá àwọn baba yín dá ṣẹ lórí yín, yóo sì fi ìfẹ́ ńlá rẹ̀ hàn yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún wọn. Yóo fẹ́ràn yín, yóo bukun yín, yóo sọ yín di pupọ, yóo bukun àwọn ọmọ yín, ati èso ilẹ̀ yín, ati ọkà yín, ọtí waini yín, ati òróró yín; yóo bukun àwọn mààlúù yín, yóo sì mú kí àwọn ẹran ọ̀sìn yín kéékèèké pọ̀ sí i, ní ilẹ̀ tí ó ti búra láti fún àwọn baba yín. OLUWA yóo bukun yín ju gbogbo àwọn eniyan yòókù lọ; kò ní sí ọkunrin kan tabi obinrin kan tí yóo yàgàn láàrin yín, tabi láàrin àwọn ẹran ọ̀sìn yín. OLUWA yóo mú gbogbo àrùn kúrò lọ́dọ̀ yín, kò sì ní fi ẹyọ kan ninu gbogbo àwọn àrùn burúkú ilẹ̀ Ijipti, tí ẹ mọ̀, ba yín jà. Ṣugbọn yóo dà wọ́n bo àwọn tí wọ́n kórìíra yín. Píparun ni ẹ óo pa gbogbo àwọn eniyan tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fi lé yín lọ́wọ́ run, ẹ kò gbọdọ̀ ṣàánú wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ kò gbọdọ̀ bọ àwọn oriṣa wọn, nítorí ohun ìkọsẹ̀ ni wọn yóo jẹ́ fun yín. “Bí ẹ bá rò ní ọkàn yín pé àwọn eniyan wọnyi pọ̀ jù yín lọ, ati pé báwo ni ẹ ṣe lè lé wọn jáde, ẹ ranti ohun tí OLUWA Ọlọrun yín ṣe sí Farao ati gbogbo ilẹ̀ Ijipti. Nítorí náà, ẹ kò gbọdọ̀ bẹ̀rù wọn. Ẹ ranti àwọn àrùn burúkú tí ẹ fi ojú ara yín rí, àwọn àmì ati àwọn iṣẹ́ ìyanu ati iṣẹ́ agbára tí OLUWA Ọlọrun yín ṣe kí ó tó kó yín jáde. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni OLUWA Ọlọrun yín yóo ṣe sí gbogbo àwọn eniyan tí ẹ̀ ń bẹ̀rù. OLUWA Ọlọrun yín yóo rán agbọ́n sí wọn títí tí gbogbo àwọn tí wọ́n bá farapamọ́ fun yín yóo fi parun. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ẹ̀rù wọn bà yín, nítorí pé Ọlọrun tí ó tóbi, tí ó sì ní ẹ̀rù ni OLUWA Ọlọrun yín tí ó wà láàrin yín. Díẹ̀díẹ̀ ni Ọlọrun yóo lé àwọn orílẹ̀-èdè yìí lọ. Kìí ṣe ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni ẹ óo pa gbogbo wọn run, kí àwọn ẹranko burúkú má baà pọ̀ ní ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì ju agbára yín lọ. Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun yín yóo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́, yóo sì mú kí ìdàrúdàpọ̀ bẹ́ sílẹ̀ ní ààrin wọn títí tí wọn yóo fi parun. Yóo fi àwọn ọba wọn lé yín lọ́wọ́, ẹ óo sì pa orúkọ wọn run ní gbogbo ayé, kò ní sí ẹyọ ẹnìkan tí yóo lè dojú kọ yín títí tí ẹ óo fi pa wọ́n run. Sísun ni kí ẹ sun gbogbo àwọn ère oriṣa wọn; ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò wúrà tabi fadaka tí ó wà lára wọn. Ẹ kò gbọdọ̀ kó wọn fún ara yín, kí wọn má baà di ohun ìkọsẹ̀ fun yín, nítorí ohun ìríra ni wọ́n lójú OLUWA Ọlọrun yín. Ẹ kò sì gbọdọ̀ mú ohun ìríra wọ ilé yín, kí ẹ má baà di ẹni ìfibú gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti jẹ́ ohun ìfibú. Ẹ níláti kórìíra wọn, kí ẹ sì yàgò fún wọn, nítorí ohun ìfibú ni wọ́n. “Ẹ gbọdọ̀ ṣọ́ra, kí ẹ sì máa pa gbogbo òfin tí mo fun yín lónìí mọ́, kí ẹ lè wà láàyè, kí ẹ lè máa bí sí i, kí ẹ sì lè lọ gba ilẹ̀ tí OLUWA ti búra láti fún àwọn baba yín. Ẹ ranti gbogbo ọ̀nà tí OLUWA Ọlọrun yín ti mú yín tọ̀ ninu aṣálẹ̀ fún ogoji ọdún yìí wá, láti tẹ orí yín ba; ó dán yín wò láti rí ọkàn yín, bóyá ẹ óo pa òfin rẹ̀ mọ́ tabi ẹ kò ní pa á mọ́. Ó tẹ orí yín ba, ó jẹ́ kí ebi pa yín, ó fi mana tí ẹ̀yin ati àwọn baba yín kò mọ̀ rí bọ́ yín, kí ẹ lè mọ̀ pé kìí ṣe oúnjẹ nìkan ní o lè mú kí eniyan wà láàyè, àfi gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu OLUWA jáde. Aṣọ kò gbó mọ yín lára, bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ yín kò wú, fún odidi ogoji ọdún yìí. Nítorí náà, ẹ mọ̀ ninu ara yín pé, gẹ́gẹ́ bí baba ti máa ń bá ọmọ rẹ̀ wí ni OLUWA ń ba yín wí. Nítorí náà, ẹ pa òfin OLUWA Ọlọrun yín mọ́, nípa rírìn ní ọ̀nà rẹ̀ ati bíbẹ̀rù rẹ̀. Nítorí pé ilẹ̀ dáradára ni ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín ń mu yín lọ. Ó kún fún ọpọlọpọ adágún omi, ati orísun omi tí ó ń tú jáde ninu àwọn àfonífojì ati lára àwọn òkè. Ilẹ̀ tí ó kún fún ọkà ati baali, ọgbà àjàrà ati igi ọ̀pọ̀tọ́, ati igi pomegiranate, ilẹ̀ tí ó kún fún igi olifi ati oyin. Ilẹ̀ tí ẹ óo ti máa jẹun, tí kò ní sí ọ̀wọ́n oúnjẹ, níbi tí ẹ kò ní ṣe aláìní ohunkohun. Ilẹ̀ tí òkúta rẹ̀ jẹ́ irin, tí ẹ óo sì máa wa idẹ lára àwọn òkè rẹ̀. Nígbà tí ẹ bá jẹun, tí ẹ yó, ẹ óo dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA Ọlọrun yín fún ilẹ̀ dáradára tí ó fun yín. “Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má gbàgbé OLUWA Ọlọrun yín, nípa àìpa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀ mọ́, ati ìdájọ́ rẹ̀ tí mo fun yín lónìí, kí ó má jẹ́ pé, nígbà tí ẹ bá jẹun, tí ẹ yó tán, tí ẹ ti kọ́ àwọn ilé dáradára, tí ẹ sì ń gbé inú wọn, nígbà tí agbo mààlúù yín ati agbo aguntan yín bá pọ̀ sí i, tí wúrà ati fadaka yín náà sì pọ̀ sí i, tí ohun gbogbo tí ẹ ní bá pọ̀ sí i, kí ìgbéraga má gba ọkàn yín, kí ẹ sì gbàgbé OLUWA Ọlọrun yín, tí ó mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, níbi tí ẹ ti ń ṣe ẹrú. Ẹni tí ó mú yín la aṣálẹ̀ ńlá tí ó bani lẹ́rù já, aṣálẹ̀ tí ó kún fún ejò olóró ati àkeekèé, tí ilẹ̀ rẹ̀ gbẹ, tí kò sì sí omi, OLUWA tí ó mú omi jáde fun yín láti inú akọ òkúta, ẹni tí ó fi mana tí àwọn baba yín kò jẹ rí bọ́ yín ninu aṣálẹ̀, kí ó lè tẹ orí yín ba, kí ó sì dán yín wò láti ṣe yín ní rere níkẹyìn. Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má baà sọ ninu ọkàn yín pé agbára yín, ati ipá yín ni ó mú ọrọ̀ yìí wá fun yín. Ẹ ranti OLUWA Ọlọrun yín nítorí òun ni ó fun yín ní agbára láti di ọlọ́rọ̀, kí ó lè fìdí majẹmu tí ó fi ìbúra bá àwọn baba yín dá múlẹ̀, bí ó ti rí lónìí. Ṣugbọn, mò ń kìlọ̀ fun yín dáradára lónìí pé, bí ẹ bá gbàgbé OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ̀ ń sá káàkiri tọ àwọn oriṣa lẹ́yìn, tí ẹ sì ń bọ wọ́n, píparun ni ẹ óo parun. Gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA parun fun yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà yóo parun, nítorí pé ẹ kọ̀, ẹ kò gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín. “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ óo la odò Jọdani kọjá sí òdìkejì lónìí, ẹ óo sì gba ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n pọ̀ jù yín lọ, tí wọ́n sì lágbára jù yín lọ. Àwọn ìlú wọn tóbi, tí odi tí wọ́n mọ yí wọn ká sì ga kan ojú ọ̀run. Àwọn eniyan náà pọ̀, wọ́n ṣígbọnlẹ̀. Àwọn òmìrán tíí ṣe ìran Anakimu ni wọ́n. Àwọn tí ẹ ti mọ̀, tí ẹ sì ti ń gbọ́ nípa wọn pé, ‘Ta ni ó lè dúró níwájú àwọn ìran Anaki?’ Nítorí náà, kí ẹ mọ̀ lónìí pé, OLUWA Ọlọrun yín ni ó ń lọ níwájú yín, bíi iná ajónirun. Yóo pa wọ́n run, yóo sì tẹ orí wọn ba fun yín, nítorí náà, kíá ni ẹ óo lé wọn jáde, tí ẹ óo sì pa wọ́n run, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti ṣe ìlérí fun yín. “Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá lé wọn jáde fun yín, ẹ má ṣe wí ninu ọkàn yín pé, ‘Nítorí òdodo wa ni OLUWA ṣe mú wa wá láti gba ilẹ̀ yìí, bẹ́ẹ̀ sì ni nítorí ìwà burúkú àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi ni OLUWA ṣe lé wọn jáde fún wa.’ Kì í ṣe nítorí ìwà òdodo yín, tabi ìdúróṣinṣin ọkàn yín ni ẹ óo fi rí ilẹ̀ náà gbà; ṣugbọn nítorí ìwà burúkú àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi ni OLUWA Ọlọrun yín fi ń lé wọn jáde fun yín, kí ó lè mú ìlérí tí ó fi ìbúra ṣe fún Abrahamu ati Isaaki ati Jakọbu, àwọn baba yín, ṣẹ. Nítorí náà, ẹ mọ̀ dájú pé, kì í ṣe nítorí ìwà òdodo yín ni OLUWA Ọlọrun yín fi ń fun yín ní ilẹ̀ dáradára yìí, nítorí pé, olórí kunkun eniyan ni yín. “Ẹ ranti, ẹ má sì ṣe gbàgbé, bí ẹ ti mú OLUWA Ọlọrun yín bínú ninu aṣálẹ̀, láti ọjọ́ tí ẹ ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti títí tí ẹ fi dé ibí yìí ni ẹ̀ ń ṣe oríkunkun sí OLUWA. Àní, ní òkè Horebu, ẹ mú kí inú bí OLUWA, tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi fẹ́ pa yín run. Nígbà tí mo gun orí òkè lọ, láti gba tabili òkúta, tíí ṣe majẹmu tí OLUWA ba yín dá, mo wà ní orí òkè náà fún ogoji ọjọ́, láìjẹ, láìmu. OLUWA fún mi ní àwọn tabili òkúta meji náà, tí Ọlọrun fúnrarẹ̀ fi ọwọ́ ara rẹ̀ kọ. Gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó ba yín sọ láti ààrin iná, ní ọjọ́ tí ẹ péjọ sí ẹsẹ̀ òkè náà ni ó wà lára àwọn tabili náà. Lẹ́yìn ogoji ọjọ́, OLUWA kó àwọn tabili òkúta náà, tíí ṣe tabili majẹmu, fún mi. “OLUWA bá sọ fún mi pé, ‘Dìde, sọ̀kalẹ̀ kíákíá, nítorí pé àwọn eniyan rẹ, tí o kó ti Ijipti wá ti dẹ́ṣẹ̀, wọ́n ti yára yipada kúrò ní ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fún wọn, wọ́n ti yá ère tí a fi iná yọ́ fún ara wọn.’ “OLUWA tún sọ fún mi pé, ‘Mo ti rí i pé olórí kunkun ni àwọn eniyan wọnyi. Fi mí sílẹ̀, jẹ́ kí n pa wọ́n run, kí n sì pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò láyé. N óo sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè tí yóo tóbi, tí yóo sì lágbára jù wọ́n lọ.’ “Mo bá gbéra, mo sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè pẹlu àwọn tabili òkúta mejeeji tí a kọ majẹmu náà sí ní ọwọ́ mi. Iná sì ń jó lórí òkè náà. Ojú tí n óo gbé sókè, mo rí i pé ẹ ti ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun yín, ẹ ti yá ère wúrà tí ẹ fi iná yọ́, ẹ ti yára yipada kúrò ní ọ̀nà tí OLUWA Ọlọrun yín pa láṣẹ fun yín. Mo bá mú àwọn tabili mejeeji, mo là wọ́n mọ́lẹ̀, mo sì fọ́ wọn lójú yín. Mo bá dọ̀bálẹ̀ gbalaja níwájú OLUWA bíi ti àkọ́kọ́, fún ogoji ọjọ́; n kò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì mu, nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ ti dá, tí ẹ ṣe ohun tí ó burú níwájú OLUWA, tí ẹ sì mú un bínú. Nítorí inú tí OLUWA ń bí si yín ati inú rẹ̀ tí kò dùn sí yín bà mí lẹ́rù, nítorí ó ti ṣetán láti pa yín run. Ṣugbọn OLUWA tún gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi nígbà náà. Inú bí OLUWA sí Aaroni tóbẹ́ẹ̀ tí OLUWA fi ṣetán láti pa á run, ṣugbọn mo gbadura fún Aaroni nígbà náà. Mo bá gbé ère ọmọ mààlúù tí ẹ yá, tí ó jẹ́ ohun ẹ̀ṣẹ̀, mo dáná sun ún, mo lọ̀ ọ́ lúbúlúbú, mo sì dà á sinu odò tí ń ṣàn wá láti orí òkè. “Bẹ́ẹ̀ ni ẹ mú OLUWA bínú ní Tabera ati ní Masa, ati ni Kibiroti Hataafa. Bákan náà ni ẹ ṣe ní Kadeṣi Banea, nígbà tí OLUWA ran yín lọ, tí ó ní kí ẹ lọ gba ilẹ̀ tí òun ti fi fun yín. Ẹ ṣe orí kunkun sí àṣẹ OLUWA Ọlọrun yín, ẹ kò gbà á gbọ́, ẹ kò sì tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ̀. Láti ìgbà tí mo ti mọ̀ yín, kò sí ìgbà kan tí ẹ kò ṣe orí kunkun sí OLUWA. “Mo bá dọ̀bálẹ̀ gbalaja níwájú rẹ̀ fún ogoji ọjọ́ nítorí pé ó pinnu láti pa yín run. Mo gbadura sí OLUWA, mo ní, ‘OLUWA Ọlọrun, má ṣe pa àwọn eniyan rẹ run. Ohun ìní rẹ ni wọ́n, àwọn tí o ti fi agbára rẹ rà pada, tí o fi ipá kó jáde láti ilẹ̀ Ijipti. Ranti Abrahamu ati Isaaki ati Jakọbu, àwọn iranṣẹ rẹ. Má wo ti oríkunkun àwọn eniyan wọnyi, tabi ìwà burúkú wọn, ati ẹ̀ṣẹ̀ wọn,’ kí àwọn ará ilẹ̀ tí o ti kó wa wá má baà wí pé, ‘OLUWA kò lè mú wọn lọ sí ilẹ̀ tí ó ṣèlérí fún wọn ati pé ó kórìíra wọn, ni ó ṣe kó wọn wá sinu aṣálẹ̀ láti pa wọ́n. Nítorí pé, eniyan rẹ ni wọ́n, ohun ìní rẹ ni wọ́n sì jẹ́, àwọn tí o fi agbára ńlá ati ipá kó jáde.’ “OLUWA sọ fún mi pé, ‘Gbẹ́ tabili òkúta meji bíi ti àkọ́kọ́, fi igi kan àpótí kan kí o sì gun orí òkè tọ̀ mí wá. N óo kọ ohun tí mo kọ sí ara àwọn tabili ti àkọ́kọ́ tí o fọ́ sí ara wọn, o óo sì kó wọn sinu àpótí náà.’ “Mo bá fi igi akasia kan àpótí kan, mo sì gbẹ́ tabili òkúta meji bíi ti àkọ́kọ́, mo gun orí òkè lọ pẹlu àwọn tabili náà lọ́wọ́ mi. OLUWA bá kọ àwọn òfin mẹ́wàá tí ó kọ sí ara àwọn tabili àkọ́kọ́ sára àwọn tabili náà, ó sì kó wọn fún mi. Àwọn òfin mẹ́wàá yìí ni OLUWA sọ fun yín lórí òkè láti ààrin iná ní ọjọ́ tí ẹ péjọ sí ẹsẹ̀ òkè náà. Mo gbéra, mo sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè wá, mo sì kó àwọn tabili náà sinu àpótí tí mo kàn, wọ́n sì wà níbẹ̀ bí OLUWA ti pàṣẹ fún mi.” (Àwọn eniyan Israẹli rìn láti Beeroti Benejaakani lọ sí Mosera, ibẹ̀ ni Aaroni kú sí, tí wọ́n sì sin ín sí. Eleasari ọmọ rẹ̀ sì ń ṣe iṣẹ́ alufaa dípò rẹ̀. Wọ́n gbéra láti ibẹ̀, wọ́n lọ sí Gudigoda. Láti Gudigoda, wọ́n lọ sí Jotibata, ilẹ̀ tí ó kún fún ọpọlọpọ odò tí ń ṣàn. Ní àkókò yìí, OLUWA ya àwọn ẹ̀yà Lefi sọ́tọ̀ láti máa gbé Àpótí Majẹmu OLUWA, ati láti máa dúró níwájú OLUWA láti ṣe iṣẹ́ ìsìn, ati láti máa yin orúkọ rẹ̀, títí di òní olónìí. Nítorí náà ni àwọn ẹ̀yà Lefi kò fi ní ìpín tabi ogún pẹlu àwọn arakunrin wọn. OLUWA ni ìpín wọn gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun yín ti wí fún wọn.) “Mo wà ní orí òkè fún odidi ogoji ọjọ́ gẹ́gẹ́ bíi ti àkọ́kọ́, OLUWA sì tún gbọ́ ohùn mi, ó gbà láti má pa yín run. OLUWA wí fún mi pé, ‘Gbéra, kí o máa lọ láti ṣáájú àwọn eniyan náà, kí wọ́n lè lọ gba ilẹ̀ tí mo búra fún wọn pé n óo fún wọn.’ “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan Israẹli, kò sí ohun tí OLUWA Ọlọrun yín fẹ́ kí ẹ ṣe, àfi pé kí ẹ bẹ̀rù rẹ̀, kí ẹ máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀, kí ẹ fẹ́ràn rẹ̀ pẹlu gbogbo ọkàn yín ati ẹ̀mí yín, kí ẹ sì pa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀, tí mo paláṣẹ fun yín lónìí mọ́, fún ire ara yín. Wò ó, OLUWA Ọlọrun yín ni ó ni ọ̀run, ati ayé ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀; sibẹsibẹ Ọlọrun fẹ́ràn àwọn baba yín tóbẹ́ẹ̀ tí ó yan ẹ̀yin arọmọdọmọ wọn, ó yàn yín láàrin gbogbo eniyan tí ó wà láyé. Nítorí náà, ẹ gbọ́ràn sí Ọlọrun lẹ́nu, kí ẹ má sì ṣe oríkunkun mọ́. Nítorí OLUWA Ọlọrun yín ni Ọlọrun àwọn ọlọ́run, ati OLUWA àwọn olúwa, Ọlọrun tí ó tóbi, tí ó lágbára, tí ó sì ní ẹ̀rù ni Ọlọrun yín, kì í ṣe ojuṣaaju, kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀. A máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́ fún àwọn aláìníbaba ati àwọn opó. Ó fẹ́ràn àwọn àlejò, a sì máa fún wọn ní oúnjẹ ati aṣọ. Nítorí náà, ẹ fẹ́ràn àwọn àlejò; nítorí pé ẹ̀yin náà ti jẹ́ àlejò ní ilẹ̀ Ijipti rí. Ẹ bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín; ẹ sìn ín, kí ẹ sì súnmọ́ ọn. Orúkọ rẹ̀ ni kí ẹ máa fi búra. Òun ni kí ẹ máa yìn, òun ni Ọlọrun yín, tí ó ṣe nǹkan ńláńlá tí ó bani lẹ́rù wọnyi fun yín, tí ẹ̀yin náà sì fi ojú ara yín rí i. Aadọrin péré ni àwọn baba ńlá yín nígbà tí wọn ń lọ sí ilẹ̀ Ijipti; ṣugbọn nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun yín ti sọ yín di pupọ bíi ìràwọ̀ ojú ọ̀run. “Nítorí náà, ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, kí ẹ sì máa tẹ̀lé gbogbo ìkìlọ̀ ati ìlànà, ati ìdájọ́, ati òfin rẹ̀ nígbà gbogbo. (Kì í ṣe àwọn ọmọ yín tí kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí mò ń sọ ni mò ń bá sọ̀rọ̀); nítorí náà, ẹ máa ṣe akiyesi ìtọ́ni OLUWA Ọlọrun yín, ati títóbi rẹ̀, ati agbára rẹ̀, ati ipá rẹ̀. Ẹ ranti gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe ní ilẹ̀ Ijipti sí ọba Farao, ati gbogbo ilẹ̀ rẹ̀. Ẹ ranti ohun tí ó ṣe sí àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Ijipti ati sí àwọn ẹṣin wọn ati kẹ̀kẹ́ ogun wọn; bí ó ti jẹ́ kí omi Òkun Pupa bò wọ́n mọ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n ń le yín bọ̀, ati bí OLUWA ti pa wọ́n run títí di òní olónìí. Ẹ ranti ohun gbogbo tí ó ṣe fun yín ninu aṣálẹ̀ títí tí ẹ fi dé ìhín; ati ohun tí ó ṣe sí Datani ati Abiramu, àwọn ọmọ Eliabu, ọmọ ọmọ Reubẹni. Ẹ ranti bí ilẹ̀ ti lanu, tí ó sì gbé wọn mì ati àwọn ati gbogbo ìdílé wọn, ati àgọ́ wọn, ati gbogbo iranṣẹ ati ẹran ọ̀sìn wọn, láàrin gbogbo Israẹli. Ẹ ti fi ojú rí gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí OLUWA ṣe. “Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ pa gbogbo òfin tí mo fun yín lónìí mọ́ kí ẹ lè ní agbára tó láti gba ilẹ̀ tí ẹ̀ ń rékọjá lọ láti gbà. Kí ẹ lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí OLUWA ti búra fún àwọn baba yín pé òun yóo fún wọn ati àwọn arọmọdọmọ wọn. Ilẹ̀ tí ó lọ́ràá tí ó sì ní ẹ̀tù lójú tí ó kún fún wàrà ati oyin. Nítorí pé, ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ láti gbà yìí, kò rí bí ilẹ̀ Ijipti níbi tí ẹ ti jáde wá; níbi tí ó jẹ́ pé nígbà tí ẹ bá gbin ohun ọ̀gbìn yín tán, ẹ óo ṣe wahala láti bu omi rin ín, bí ìgbà tí à ń bu omi sí ọgbà ẹ̀fọ́. Ṣugbọn ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà yìí jẹ́ ilẹ̀ tí ó kún fún òkè ati àfonífojì. Láti ojú ọ̀run ni òjò ti ń rọ̀ sí i. OLUWA Ọlọrun yín tìkararẹ̀ ni ó ń tọ́jú rẹ̀, tí ó sì ń mójútó o láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún títí dé òpin. “Tí ẹ bá tẹ̀lé òfin mi tí mo fun yín lónìí, tí ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ sì sìn ín pẹlu gbogbo ọkàn ati ẹ̀mí yín, yóo rọ òjò sórí ilẹ̀ yín ní àkókò rẹ̀, ati òjò àkọ́rọ̀ ati ti àrọ̀kẹ́yìn, kí ẹ baà lè kórè ọkà, ọtí waini, ati òróró olifi yín. Yóo mú kí koríko dàgbà ninu pápá fún àwọn ẹran ọ̀sìn yín, ẹ óo jẹ, ẹ óo sì yó. Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ̀tàn má baà wọ inú ọkàn yín, kí ẹ má baà yipada sí àwọn oriṣa, kí ẹ sì máa bọ wọ́n. Kí inú má baà bí Ọlọrun si yín, kí o má baà mú kí òjò dáwọ́ dúró, kí ilẹ̀ yín má sì so èso mọ́; kí ẹ má baà parun kíákíá lórí ilẹ̀ tí OLUWA fun yín. “Nítorí náà, ohun tí mo sọ fun yín yìí, ẹ pa á mọ́ sinu ọkàn yín. Ẹ fi ọ̀rọ̀ náà sọ́kàn, ẹ so ó mọ́ ọwọ́ yín gẹ́gẹ́ bí àmì, kí ẹ fi ṣe ọ̀já ìgbàjú, kí ó wà ní agbede meji ojú yín mejeeji. Kí ẹ fi kọ́ àwọn ọmọ yín dáradára, ẹ máa fi ṣe ọ̀rọ̀ sọ nígbà tí ẹ bá jókòó ninu ilé yín ati ìgbà tí ẹ bá ń rìn lọ lójú ọ̀nà, ati ìgbà tí ẹ bá dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn yín ati nígbà tí ẹ bá dìde. Ẹ kọ ọ́ sí ara òpó ìlẹ̀kùn ilé yín ati sí ara ẹnu ọ̀nà àbájáde ilé yín. Kí ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun búra fún àwọn baba yín, pé òun yóo fún wọn títí lae, níwọ̀n ìgbà tí ojú ọ̀run bá wà lókè. “Tí ẹ bá ṣọ́ra, tí ẹ sì pa gbogbo òfin tí mo fun yín mọ́, tí ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ̀ ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀, tí ẹ sì súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí, OLUWA yóo lé àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi jáde fun yín, ẹ óo sì gba ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n pọ̀ jù yín lọ, tí wọ́n sì lágbára jù yín lọ. Gbogbo ibi tí ẹsẹ̀ yín bá tẹ̀, ẹ̀yin ni ẹ óo ni ín. Ilẹ̀ yín yóo bẹ̀rẹ̀ láti aṣálẹ̀ Lẹbanoni, ati láti odò Yufurate títí dé Òkun tí ó wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn. Kò ní sí ẹnikẹ́ni tí yóo lè dojú kọ yín, OLUWA Ọlọrun yín yóo mú kí ẹ̀rù yín máa ba gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ tí ẹ óo máa rìn kọjá, jìnnìjìnnì yín yóo sì máa bò wọ́n, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti ṣe ìlérí fun yín. “Ẹ wò ó, mo gbé ibukun ati ègún kalẹ̀ níwájú yín lónìí. Ibukun ni fun yín bí ẹ bá tẹ̀lé òfin OLUWA Ọlọrun yín, tí mo fun yín lónìí yìí. Ṣugbọn ègún ni fun yín bí ẹ kò bá tẹ̀lé òfin OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ bá yà kúrò lójú ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fun yín lónìí, tí ẹ bá ń sin àwọn oriṣa tí ẹ kò mọ̀ rí. Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá mú yín dé ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ, tí ẹ óo sì gbà, ẹ kéde ibukun náà lórí òkè Gerisimu, kí ẹ sì kéde ègún náà lórí òkè Ebali. Òkè Gerisimu ati òkè Ebali wà ní òdìkejì Jọdani, ní ojú ọ̀nà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, ní ilẹ̀ àwọn ará Kenaani tí wọn ń gbé Araba, ní òdìkejì Giligali, lẹ́bàá igi Oaku More. Nítorí ẹ óo la odò Jọdani kọjá láti lọ gba ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fi fun yín. Nígbà tí ẹ bá gbà á tán, tí ẹ̀ ń gbé inú rẹ̀, ẹ ṣọ́ra, kí ẹ máa tẹ̀lé gbogbo ìlànà ati òfin tí mo fi lélẹ̀ níwájú yín lónìí. “Àwọn ìlànà ati òfin, tí ẹ óo máa tẹ̀lé lẹ́sẹẹsẹ, ní gbogbo ọjọ́ ayé yín ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín ti fi fun yín láti gbà, nìyí: Gbogbo ibi tí àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ óo lé kúrò ti ń sin oriṣa wọn ni kí ẹ wó lulẹ̀, ati àwọn tí wọ́n wà lórí òkè ńlá, ati àwọn tí wọ̀n wà lórí àwọn òkè kéékèèké, ati àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ igi tútù. Ẹ wó gbogbo pẹpẹ wọn lulẹ̀, ẹ fọ́ gbogbo òpó wọn, ẹ dáná sun àwọn ère oriṣa Aṣera wọn, ẹ gé gbogbo àwọn ère oriṣa wọn lulẹ̀, kí ẹ sì pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò níbẹ̀. “Ẹ kò gbọdọ̀ máa sin OLUWA Ọlọrun yín káàkiri bí wọ́n ti ń ṣe. Ṣugbọn ibi tí OLUWA bá yàn láti gbé ibùjókòó rẹ̀ kà láàrin gbogbo àwọn ẹ̀yà, ibẹ̀ ni kí ẹ máa lọ. Ibẹ̀ ni kí ẹ máa mú gbogbo ẹbọ sísun yín, ati àwọn ẹbọ yòókù wá, ati ìdámẹ́wàá yín, ati ọrẹ àtinúwá yín, ati ẹ̀jẹ́ yín tí ẹ bá jẹ́ fún OLUWA, ati àkọ́bí mààlúù yín, ati ti aguntan yín. Ibẹ̀ ni ẹ̀yin ati gbogbo ìdílé yín yóo ti jẹun níwájú OLUWA Ọlọrun yín, inú yín yóo sì dùn nítorí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín tí OLUWA ti fi ibukun sí. “Ẹ kò gbọdọ̀ máa ṣe bí a ti ń ṣe níbí lónìí, tí olukuluku ń ṣe èyí tí ó dára lójú ara rẹ̀. Nítorí pé ẹ kò tíì dé ibi ìsinmi ati ilẹ̀ ìní tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fun yín. Ṣugbọn nígbà tí ẹ bá rékọjá sí òdìkejì odò Jọdani, tí ẹ sì ń gbé ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fun yín, nígbà tí ó bá sì fun yín ní ìsinmi, tí ẹ bá bọ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá tí ó yí yín ká, tí ẹ sì wà ní àìléwu, ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn láti fi ibùgbé rẹ̀ sí nígbà náà, ni kí ẹ kó gbogbo àwọn nǹkan tí mo pa láṣẹ fun yín wa, ẹbọ sísun yín ati àwọn ẹbọ mìíràn, ìdámẹ́wàá yín, ati ọrẹ, ati gbogbo ẹ̀jẹ́ yín tí ẹ bá jẹ́ fún OLUWA. Ẹ óo sì máa yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín, ati ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin, ati àwọn iranṣẹkunrin yín, ati àwọn iranṣẹbinrin yín, ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà láàrin ìlú yín, nítorí pé wọn kò ní ìpín ninu ilẹ̀ yín. Ẹ ṣọ́ra, ẹ má máa rú ẹbọ sísun yín níbikíbi tí ẹ bá ti rí. Ṣugbọn ibi tí OLUWA yín bá yàn láàrin ẹ̀yà yín, ni kí ẹ ti máa rú ẹbọ sísun yín, kí ẹ sì máa ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fun yín níbẹ̀. “Ṣugbọn ẹ lè pa iye ẹran tí ó bá wù yín, kí ẹ sì jẹ ẹ́ níbikíbi tí ẹ bá ń gbé, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun yín bá ti bukun yín tó. Ẹni tí ó mọ́, ati ẹni tí kò mọ́ lè jẹ ninu ẹran náà bí ìgbà tí eniyan ń jẹ ẹran ẹtu tabi ti àgbọ̀nrín. Ẹ̀jẹ̀ wọn nìkan ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ, dídà ni kí ẹ dà á sílẹ̀ bí ẹni da omi. Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ninu ohun tí o bá jẹ́ ìdámẹ́wàá yín ninu ìlú yín, kì báà ṣe ìdámẹ́wàá ọkà yín, tabi ti ọtí waini, tabi ti òróró, tabi ti àkọ́bí mààlúù, tabi ti ewúrẹ́, tabi ti aguntan, tabi ohunkohun tí ẹ bá fi san ẹ̀jẹ́ fún OLUWA, tabi ọrẹ àtinúwá yín tabi ọrẹ àkànṣe yín. Níwájú OLUWA Ọlọrun yín, níbikíbi tí ó bá yàn, ni kí ẹ ti jẹ ẹ́; ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín, lọkunrin ati lobinrin, ati àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin yín, ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n bá wà ninu ìlú yín. Kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín ninu ohun gbogbo tí ẹ bá ń ṣe. Kí ẹ rí i dájú pé, ẹ kò gbàgbé àwọn ọmọ Lefi níwọ̀n ìgbà tí ẹ bá wà lórí ilẹ̀ yín. “Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá mú kí ilẹ̀ yín pọ̀ sí i gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fun yín, tí ẹran bá wù yín jẹ, ẹ lè jẹ ẹran dé ibi tí ó bá wù yín. Bí ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun bá jìnnà pupọ sí yín, ẹ mú mààlúù tabi aguntan láti inú agbo ẹran tí OLUWA fi fun yín, kí ẹ pa á bí mo ti pa á láṣẹ fun yín, kí ẹ sì jẹ ohunkohun tí ọkàn yín bá fẹ́ láti jẹ láàrin àwọn ìlú yín. Ati ẹni tí ó mọ́ ati ẹni tí kò mọ́ ni ó lè jẹ ninu ẹran náà bí ìgbà tí eniyan ń jẹ ẹran ẹtu tabi ti àgbọ̀nrín. Kí ẹ rí i dájú pé ẹ kò jẹ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ nítorí pé ninu ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí wà, ẹ kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹran pẹlu ẹ̀mí rẹ̀. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, dídà ni kí ẹ dà á sílẹ̀ bí omi. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́, kí ó lè dára fún ẹ̀yin ati àwọn arọmọdọmọ yín nígbà tí ẹ bá ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú OLUWA. Ẹ gbọdọ̀ mú àwọn ohun ìyàsímímọ́ tí ẹ ní, ati àwọn ẹ̀jẹ́ yín lọ sí ibi tí OLUWA ti yàn fún ìrúbọ. Kí ẹ rú ẹbọ sísun yín ati ẹran ati ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lórí pẹpẹ OLUWA Ọlọrun yín, ẹ da ẹ̀jẹ̀ ẹbọ yín sórí pẹpẹ OLUWA Ọlọrun yín, kí ẹ sì jẹ ara ẹran rẹ̀. Ẹ kíyèsára, kí ẹ rí i dájú pé ẹ pa àwọn ohun tí mo pa láṣẹ fun yín mọ́, kí ó lè dára fún ẹ̀yin ati àwọn arọmọdọmọ yín títí lae. “Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá pa àwọn orílẹ̀-èdè run níbi gbogbo tí ẹ bá lọ, tí ẹ bá bá wọn jagun tí ẹ gba ilẹ̀ wọn, tí ẹ sì ń gbé ibẹ̀; ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má baà ṣìnà, lẹ́yìn tí Ọlọrun bá ti pa wọ́n run tán, kí ẹ má baà bèèrè pé, ‘Báwo ni àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi ṣe ń bọ àwọn oriṣa wọn? Kí àwa náà lè máa ṣe bẹ́ẹ̀.’ Ẹ kò gbọdọ̀ sin OLUWA Ọlọrun yín bí wọn ti ń bọ àwọn oriṣa wọn nítorí oríṣìíríṣìí ohun tí ó jẹ́ ìríra lójú OLUWA ni wọ́n máa ń ṣe. Wọn a máa fi àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin wọn rúbọ sí oriṣa wọn. “Gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fun yín ni kí ẹ fọkàn sí, kí ẹ sì ṣe é, ẹ kò gbọdọ̀ fi kún un, ẹ kò sì gbọdọ̀ mú kúrò ninu rẹ̀. “Bí ẹnìkan bá di wolii láàrin yín, tabi tí ó ń lá àlá, tí ń sọ nípa àmì ati iṣẹ́ ìyanu tí yóo ṣẹlẹ̀, tí gbogbo nǹkan tí ó ń sọ sì ń rí bẹ́ẹ̀; bí ó bá wí pé kí ẹ wá lọ bọ oriṣa mìíràn tí ẹ kò mọ̀ rí, ẹ kò gbọdọ̀ dá wolii tabi alálàá náà lóhùn, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín ń dán yín wò ni, láti mọ̀ bóyá ẹ fẹ́ràn òun tọkàntọkàn. OLUWA Ọlọrun yín ni kí ẹ máa tẹ̀lé, òun ni kí ẹ máa bẹ̀rù. Ẹ máa pa òfin rẹ̀ mọ́, kí ẹ sì máa gbọ́ tirẹ̀; ẹ máa sìn ín, kí ẹ sì súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí. Ṣugbọn pípa ni kí ẹ pa wolii tabi alálàá náà, nítorí pé ó ń kọ yín láti ṣọ̀tẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun tí ó kó yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, tí ó sì rà yín pada kúrò ní oko ẹrú. Ẹ níláti pa olúwarẹ̀ nítorí pé ó fẹ́ mú kí ẹ kọ ẹ̀yìn sí ọ̀nà tí OLUWA Ọlọrun yín ti là sílẹ̀ fun yín láti máa rìn, nítorí náà ẹ gbọdọ̀ yọ nǹkan burúkú náà kúrò láàrin yín. “Bí ẹnikẹ́ni bá ń tàn ọ́ níkọ̀kọ̀ pé kí o lọ bọ oriṣa-koriṣa kan, tí ìwọ tabi àwọn baba rẹ kò bọ rí, olúwarẹ̀ kì báà jẹ́ arakunrin rẹ, tíí ṣe ọmọ ìyá rẹ, tabi ọmọ rẹ, lọkunrin tabi lobinrin, tabi aya rẹ, tí ó dàbí ẹyin ojú rẹ, tabi ọ̀rẹ́ rẹ tí o fẹ́ràn ju ẹ̀mí ara rẹ lọ; oriṣa yìí kì báà jẹ́ èyí tí ó wà nítòsí, tí àwọn ará agbègbè yín ń bọ, tabi èyí tí ó jìnnà réré, tí àwọn tí wọ́n wà ní ilẹ̀ òkèèrè ń bọ. O kò gbọdọ̀ gbọ́ tirẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ dá a lóhùn. O kò gbọdọ̀ ṣàánú fún un, o kò sì gbọdọ̀ bò ó. Pípa ni kí o pa á, ìwọ gan-an ni kí o kọ́ sọ òkúta lù ú, kí àwọn eniyan yòókù tó kó òkúta bò ó. Ẹ sọ ọ́ ní òkúta pa nítorí tí ó ti gbìyànjú láti fà yín kúrò lọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun yín, tí ó mu yín jáde kúrò ní oko ẹrú ní ilẹ̀ Ijipti. Gbogbo ọmọ Israẹli yóo gbọ́, ẹ̀rù yóo sì bà wọ́n, ẹnikẹ́ni kò sì ní hu irú ìwà burúkú bẹ́ẹ̀ mọ́ láàrin yín. “Bí ẹ bá gbọ́, ní ọ̀kan ninu àwọn ìlú tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín láti máa gbé, pé, àwọn eniyan lásán kan láàrin yín ń tan àwọn ará ìlú náà jẹ, wọ́n ń wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ bọ oriṣa.’ Ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí ọ̀rọ̀ náà. Bí ó bá jẹ́ pé òtítọ́ ni, tí ó sì dáa yín lójú pé ohun ìríra bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ láàrin yín, idà ni kí ẹ fi pa àwọn tí wọn ń gbé ìlú náà. Ẹ pa wọ́n run patapata, ati gbogbo ohun tí ó wà níbẹ̀; ẹ fi idà pa gbogbo wọn ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn. Ẹ kó gbogbo ìkógun tí ẹ bá rí ninu ìlú náà jọ sí ààrin ìgboro rẹ̀, kí ẹ sì dáná sun gbogbo rẹ̀ bí ẹbọ sísun sí OLUWA Ọlọrun yín. Ìlú náà yóo di àlàpà títí lae, ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ tún un kọ́ mọ́. Àwọn ìkógun yìí jẹ́ ohun ìyàsọ́tọ̀ fún OLUWA, ẹ kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan èyíkéyìí ninu wọn kí OLUWA lè yí ibinu gbígbóná rẹ̀ pada, kí ó ṣàánú fun yín, kí ó sì mú kí ẹ pọ̀ sí i, gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún àwọn baba yín. Ẹ máa gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín, kí ẹ sì máa pa gbogbo òfin rẹ̀, tí mo fun yín lónìí mọ́, kí ẹ sì máa ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA Ọlọrun yín. “Ọmọ ni ẹ jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun yín, nítorí náà, ẹ kò gbọdọ̀ fi abẹ ya ara yín lára tabi kí ẹ fá irun yín níwájú nígbà tí ẹ bá ń ṣọ̀fọ̀ ẹni tí ó kú. Nítorí pé, ẹni ìyàsọ́tọ̀ ni yín fún OLUWA Ọlọrun yín, OLUWA ti yàn yín láti jẹ́ eniyan tirẹ̀ láàrin gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé. “Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó jẹ́ ohun ìríra. Àwọn ẹran tí ẹ lè jẹ nìwọ̀nyí: mààlúù, aguntan, ewúrẹ́, àgbọ̀nrín ati èsúó ati ìgalà, ati oríṣìí ẹranko igbó kan tí ó dàbí ewúrẹ́, ati ẹranko kan tí wọn ń pè ní Pigarigi, ati ẹfọ̀n, ati ẹtu. Àwọn ẹranko tí pátákò ẹsẹ̀ wọn là sí meji, tabi tí wọ́n bá ní ìka ẹsẹ̀, tí wọ́n sì ń jẹ àpọ̀jẹ, irú wọn ni kí ẹ máa jẹ. Ṣugbọn ninu àwọn ẹran tí wọn ń jẹ àpọ̀jẹ ati àwọn tí pátákò ẹsẹ̀ wọn là sí meji tabi tí wọ́n ní ìka ẹsẹ̀, àwọn wọnyi ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ: ràkúnmí, ati ehoro ati ẹranko kan tí ó dàbí gara. Àwọn wọnyi ń jẹ àpọ̀jẹ lóòótọ́, ṣugbọn pátákò ẹsẹ̀ wọn kò là, nítorí náà, wọ́n jẹ́ aláìmọ́ fun yín. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹlẹ́dẹ̀, lóòótọ́ ó ní ìka ẹsẹ̀, ṣugbọn kì í jẹ àpọ̀jẹ, nítorí náà, ó jẹ́ aláìmọ́ fun yín. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran ara wọn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ fara kan òkú wọn. “Ninu gbogbo àwọn abẹ̀mí tí ó wà ninu omi, àwọn wọnyi ni kí ẹ máa jẹ: gbogbo àwọn ohun tí ó bá ní lẹbẹ ati ìpẹ́ ni ẹ lè jẹ. Ṣugbọn èyíkéyìí tí kò bá ní lẹbẹ ati ìpẹ́, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ wọ́n, nítorí wọ́n jẹ́ aláìmọ́ fun yín. “Ẹ lè jẹ gbogbo àwọn ẹyẹ tí wọ́n bá mọ́. Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ jẹ àwọn ẹyẹ wọnyi: ẹyẹ idì, igún ati idì tí ń jẹ ẹja, ati àṣá gidi, ati oríṣìíríṣìí àṣá mìíràn, ati igún gidi, ati àwọn oríṣìíríṣìí igún yòókù, ati oríṣìíríṣìí àwọn ẹyẹ ìwò, ati ògòǹgò, ati òwìwí, ati ẹ̀lulùú, ati oríṣìíríṣìí àwòdì, ati òwìwí ńlá, ati òwìwí kéékèèké, ati ògbúgbú, ati ẹyẹ òfù, ati àkàlà, ati ẹyẹ ìgo, ati ẹyẹ àkọ̀, ati oríṣìíríṣìí ẹyẹ òòdẹ̀, ati ẹyẹ atọ́ka, ati àdán. “Gbogbo àwọn kòkòrò tí wọn ń fò jẹ́ aláìmọ́ fun yín, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ wọ́n. Ṣugbọn ẹ lè jẹ gbogbo àwọn ohun tí ó bá ní ìyẹ́, tí wọ́n sì mọ́. “Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó bá kú fúnrarẹ̀, ẹ lè fún àwọn àlejò tí ń gbé ààrin yín, kí ó jẹ ẹ́, tabi kí ẹ tà á fún àjèjì, nítorí pé, ẹ̀yin jẹ́ ẹni mímọ́ fún OLUWA Ọlọrun yín. “Ẹ kò gbọdọ̀ se ọmọ ewúrẹ́ ninu wàrà ọmú ìyá rẹ̀. “Ẹ gbọdọ̀ san ìdámẹ́wàá gbogbo ìkórè oko yín ní ọdọọdún. Ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun ni kí ẹ ti jẹ ìdámẹ́wàá ọkà yín, ati ti ọtí waini yín, ati ti òróró yín, ati àkọ́bí àwọn mààlúù yín, ati ti agbo ẹran yín; kí ẹ lè kọ́ láti bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín nígbà gbogbo. Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá bukun yín tán, tí ibi tí ó yàn pé kí ẹ ti máa sin òun bá jìnnà jù fun yín láti ru ìdámẹ́wàá ìkórè oko yín lọ, ẹ tà á, kí ẹ sì gba owó rẹ̀ sọ́wọ́, kí ẹ kó owó náà lọ sí ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun. Ẹ fi owó náà ra ohunkohun tí ọkàn yín bá fẹ́, ìbáà ṣe akọ mààlúù, tabi aguntan, tabi ọtí waini, tabi ọtí líle, tabi ohunkohun tí ọkàn yín bá ṣá fẹ́. Ẹ óo jẹ ẹ́ níbẹ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín, ẹ óo sì máa yọ̀, ẹ̀yin ati ìdílé yín. “Ẹ kò gbọdọ̀ gbàgbé àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà láàrin yín nítorí pé, wọn kò ní ìpín tabi ohun ìní láàrin yín. Ní òpin ọdún kẹtakẹta, ẹ níláti kó ìdámẹ́wàá ìkórè gbogbo oko yín ti ọdún náà jọ, kí ẹ kó wọn kalẹ̀ ninu gbogbo àwọn ìlú yín. Kí àwọn ọmọ Lefi, tí wọn kò ní ìpín ati ohun ìní láàrin yín, ati àwọn àlejò, ati àwọn aláìníbaba, ati àwọn opó tí wọ́n wà ninu àwọn ìlú yín jẹ, kí wọ́n sì yó, kí OLUWA Ọlọrun yín lè bukun yín ninu gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín. “Ní ọdún keje-keje ni kí ẹ máa ṣe ìdásílẹ̀. Bí ẹ óo ṣe máa ṣe ìdásílẹ̀ náà nìyí: ẹnikẹ́ni tí aládùúgbò rẹ̀, tíí ṣe arakunrin rẹ̀, bá jẹ ní gbèsè kò ní gba ohun tí aládùúgbò rẹ̀ jẹ ẹ́ mọ́, nítorí pé, a ti kéde ìdásílẹ̀ tíí ṣe ti OLUWA. Bí ó bá jẹ́ pé àlejò ni ó jẹ ẹni náà ní gbèsè, olúwarẹ̀ lè gbà á, ṣugbọn ohunkohun tí ó bá jẹ́ tiyín, tí ó wà lọ́wọ́ arakunrin yín, ẹ kò gbọdọ̀ gbà á pada. “Ṣugbọn kò ní sí ẹnikẹ́ni ninu yín tí yóo jẹ́ talaka, nítorí pé, OLUWA Ọlọrun yín yóo bukun yín, ní ilẹ̀ tí ó fun yín láti gbà, bí ẹ bá sá ti gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ sì farabalẹ̀, ti ẹ tẹ̀lé gbogbo òfin rẹ̀ tí mo fun yín lónìí. Nítorí OLUWA Ọlọrun yín yóo bukun yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fun yín. Ẹ óo máa yá àwọn orílẹ̀-èdè ni nǹkan, ṣugbọn ẹ kò ní tọrọ lọ́wọ́ wọn. Ẹ óo máa jọba lórí ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, ṣugbọn wọn kò ní jọba lórí yín. “Bí ẹnìkan ninu yín, tí ó jẹ́ arakunrin yín, bá jẹ́ talaka, tí ó sì wà ninu ọ̀kan ninu àwọn ìlú tí ó wà ninu ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, ẹ kò gbọdọ̀ dijú sí i, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ háwọ́ sí arakunrin yín tí ó jẹ́ talaka yìí. Ẹ gbọdọ̀ lawọ́ sí i, kí ẹ sì yá a ní ohun tí ó tó láti tán gbogbo àìní rẹ̀, ohunkohun tí ó wù kí ó lè jẹ́. Ẹ ṣọ́ra, kí èròkerò má baà gba ọkàn yín, kí ẹ wí pé, ọdún keje tíí ṣe ọdún ìdásílẹ̀ ti súnmọ́ tòsí, kí ojú yín sì le sí arakunrin yín tí ó jẹ́ talaka, kí ẹ má sì fún un ní ohunkohun. Kí ó má baà ké pe OLUWA nítorí yín, kí ó sì di ẹ̀ṣẹ̀ si yín lọ́rùn. Ẹ fún un ní ohun tí ẹ bá fẹ́ fún un tọkàntọkàn, kì í ṣe pẹlu ìkùnsínú, nítorí pé, nítorí ìdí èyí ni OLUWA Ọlọrun yín yóo ṣe bukun iṣẹ́ ọwọ́ yín ati gbogbo ohun tí ẹ bá dáwọ́ lé. Nítorí pé, talaka kò ní tán lórí ilẹ̀ yín, nítorí náà ni mo ṣe ń pàṣẹ fun yín pé kí ẹ lawọ́ sí arakunrin yín, ati sí talaka ati sí aláìní ní ilẹ̀ náà. “Bí wọ́n bá ta arakunrin yín lẹ́rú fun yín, kì báà jẹ́ ọkunrin tabi obinrin, tí ó bá ti jẹ́ Heberu, ọdún mẹfa ni yóo fi sìn yín. Tí ó bá di ọdún keje, ẹ gbọdọ̀ dá a sílẹ̀, kí ó sì máa lọ. Nígbà tí ẹ bá dá a sílẹ̀ pé kí ó máa lọ, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó lọ ní ọwọ́ òfo. Ẹ gbọdọ̀ fún un ní ẹran ọ̀sìn lọpọlọpọ ati ọkà láti inú ibi ìpakà yín, ati ọtí waini. Bí OLUWA Ọlọrun yín bá ti bukun yín tó, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ ṣe fún un tó. Ẹ gbọdọ̀ ranti pé ẹ̀yin náà ti jẹ́ ẹrú rí ní ilẹ̀ Ijipti, OLUWA Ọlọrun yín ni ó rà yín pada; nítorí náà ni mo fi ń pàṣẹ fun yín lónìí. “Ṣugbọn tí ó bá wí fun yín pé, òun kò ní jáde ninu ilé yín, nítorí pé ó fẹ́ràn ẹ̀yin ati gbogbo ìdílé yín, nítorí pé ó dára fún un nígbà tí ó wà lọ́dọ̀ yín, ẹ mú ìlutí kan, kí ẹ fi lu etí rẹ̀ mọ́ ara ìlẹ̀kùn. Yóo sì jẹ́ ẹrukunrin yín títí lae. Bí ó bá sì jẹ́ obinrin ni, bákan náà ni kí ẹ ṣe fún un. Má jẹ́ kí ó ni ọ́ lára láti dá a sílẹ̀ kí ó sì máa lọ lọ́fẹ̀ẹ́, nítorí pé, ìdajì owó ọ̀yà alágbàṣe ni ó ti fi ń sìn ọ́, fún odidi ọdún mẹfa. Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ ṣe, kí OLUWA Ọlọrun yín lè bukun ohun gbogbo tí ẹ bá ń ṣe. “Gbogbo àkọ́bí tí ẹran ọ̀sìn bá bí ninu agbo ẹran yín, tí ó bá jẹ́ akọ ni ẹ gbọdọ̀ yà á sọ́tọ̀ fún OLUWA Ọlọrun. Ẹ kò gbọdọ̀ fi akọ tí ó jẹ́ àkọ́bí ninu agbo mààlúù yín ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì gbọdọ̀ rẹ́ irun àgbò tí ó jẹ́ àkọ́bí aguntan yín. Níbikíbi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn, ni ẹ ti gbọdọ̀ máa jẹ wọ́n níwájú rẹ̀, ní ọdọọdún; ẹ̀yin ati gbogbo ilé yín. Ṣugbọn bí ó bá ní àbààwọ́n kan, bóyá ó jẹ́ arọ ni, tabi afọ́jú, tabi ó ní àbààwọ́n kankan, ẹ kò gbọdọ̀ fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun yín, jíjẹ ni kí ẹ jẹ ẹ́ ní ààrin ìlú yín, ati àwọn tí wọ́n mọ́, ati àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìmọ́ ni wọ́n lè jẹ ninu rẹ̀, bí ìgbà tí eniyan jẹ ẹran èsúó tabi àgbọ̀nrín ni. Ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ nìkan ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ; dídà ni kí ẹ dà á sílẹ̀ bí omi. “Ẹ máa ranti láti máa ṣe àjọ̀dún àjọ ìrékọjá fún OLUWA Ọlọrun yín ninu oṣù Abibu nítorí ninu oṣù Abibu ni ó kó yín jáde ní ilẹ̀ Ijipti, lálẹ́. Ẹ níláti máa rú ẹbọ àjọ ìrékọjá sí OLUWA Ọlọrun yín láti inú agbo mààlúù yín, tabi agbo aguntan yín, níbi tí ó bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ burẹdi tí ó ní ìwúkàrà ninu pẹlu ẹbọ náà; ọjọ́ meje ni ẹ óo fi jẹ ẹ́ pẹlu burẹdi tí kò ní ìwúkàrà. Oúnjẹ náà jẹ́ oúnjẹ ìpọ́njú, nítorí pé ìkánjú ni ẹ fi jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti; ẹ óo sì lè máa ranti ọjọ́ náà tí ẹ kúrò ní ilẹ̀ Ijipti ní gbogbo ọjọ́ ayé yín. Wọn kò gbọdọ̀ bá ìwúkàrà lọ́wọ́ yín, ati ní gbogbo agbègbè yín, fún ọjọ́ meje. Ẹran tí ẹ bá fi rúbọ kò gbọdọ̀ ṣẹ́kù ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kinni, títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji. “Ẹ kò gbọdọ̀ rú ẹbọ àjọ ìrékọjá láàrin èyíkéyìí ninu àwọn ìlú tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fi fun yín. Àfi ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun, níbẹ̀ ni ẹ ti gbọdọ̀ máa rú ẹbọ àjọ ìrékọjá ní ìrọ̀lẹ́, nígbà tí oòrùn ń lọ wọ̀ ní àkókò tí ẹ jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. Bíbọ̀ ni kí ẹ bọ̀ ọ́, kí ẹ jẹ ẹ́ ní ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa jọ́sìn, nígbà tí ó bá sì di òwúrọ̀ ẹ óo pada lọ sinu àgọ́ yín. Ọjọ́ mẹfa ni ẹ óo fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, ní ọjọ́ keje, ẹ óo pe àpèjọ tí ó ní ọ̀wọ̀, ẹ óo sì sin OLUWA Ọlọrun yín. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà. “Ẹ óo ka ọ̀sẹ̀ meje, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ tí ẹ kọ́kọ́ ti dòjé bọ inú oko ọkà, tí ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí gé e. Nígbà náà, ẹ óo ṣe àsè àjọ ọ̀sẹ̀, tíí ṣe àjọ̀dún ìkórè fún OLUWA Ọlọrun yín; pẹlu ọrẹ àtinúwá. Ẹ óo mú ọrẹ náà wá bí OLUWA Ọlọrun yín bá ti bukun yín. Ẹ óo máa yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín, níbikíbi tí ó bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun, ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin, ati àwọn iranṣẹbinrin ati iranṣẹkunrin yín, ati àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń gbé àwọn ìlú yín; àwọn àlejò, àwọn aláìníbaba, ati àwọn opó, tí wọ́n wà láàrin yín. Ẹ ranti pé ẹ ti jẹ́ ẹrú rí ní ilẹ̀ Ijipti. Ẹ ṣọ́ra kí ẹ lè máa tẹ̀lé àwọn ìlànà wọnyi. “Ọjọ́ meje ni ẹ gbọdọ̀ máa fi se àsè àjọ̀dún àgọ́ nígbà tí ẹ bá kó ọkà yín jọ láti ibi ìpakà, tí ẹ kó ọtí waini yín jọ láti ibi ìfúntí. Ẹ máa yọ̀, bí ẹ ti ń gbádùn àjọ̀dún yín, ẹ̀yin, ati àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin ati àwọn iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin yín, àwọn ọmọ Lefi, àwọn àjèjì, àwọn aláìní baba, ati àwọn opó, tí wọ́n wà ní àwọn ìlú yín. Ọjọ́ meje ni ẹ óo fi se àsè yìí fún OLUWA Ọlọrun yín níbi tí OLUWA bá yàn pé kí ẹ ti máa jọ́sìn, nítorí OLUWA Ọlọrun yín yóo bukun gbogbo èso yín, ati gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín, tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ óo láyọ̀ gidigidi. “Ìgbà mẹta láàrin ọdún kan ni gbogbo àwọn ọkunrin yín yóo máa farahàn níwájú OLUWA níbi tí OLUWA bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun; àkókò àjọ̀dún burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, ati àkókò àjọ̀dún ìkórè, ati àkókò àjọ̀dún àgọ́. Wọn kò gbọdọ̀ farahàn níwájú OLUWA ní ọwọ́ òfo. Olukuluku ọkunrin yóo mú ọrẹ wá gẹ́gẹ́ bí ó bá ti fẹ́ ati gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun yín bá ti bukun un. “Ẹ yan àwọn adájọ́ ati àwọn olórí tí OLUWA Ọlọrun yín fi fun yín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà yín, ní àwọn ìlú yín, wọn yóo sì máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́ fún àwọn eniyan. Ẹ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ojuṣaaju, ẹ kò sì gbọdọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀; nítorí pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ a máa fọ́ ọlọ́gbọ́n lójú, a sì máa yí ẹjọ́ aláre pada sí ẹ̀bi. Ẹ̀tọ́ nìkan ṣoṣo ni kí ẹ máa ṣe, kí ẹ lè wà láàyè, kí ẹ sì lè jogún ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín. “Ẹ kò gbọdọ̀ gbin igikígi bí igi oriṣa Aṣera sí ẹ̀bá pẹpẹ OLUWA Ọlọrun yín, nígbà tí ẹ bá ń kọ́ ọ. Ẹ kò sì gbọdọ̀ ri òpó mọ́lẹ̀ kí ẹ máa bọ ọ́, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín kórìíra wọn. “Ẹ kò gbọdọ̀ fi mààlúù tabi aguntan tí ó ní àbààwọ́n rúbọ sí OLUWA Ọlọrun yín nítorí pé ohun ìríra ni ó jẹ́ fún un. “Bí ọkunrin kan tabi obinrin kan láàrin àwọn ìlú tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín bá ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA Ọlọrun yín, nípa pé ó da majẹmu rẹ̀, bí ó bá lọ bọ oriṣa, kì báà ṣe oòrùn, tabi òṣùpá, tabi ọ̀kan ninu àwọn nǹkan mìíràn tí ó wà ní ojú ọ̀run, tí mo ti pàṣẹ pé ẹ kò gbọdọ̀ bọ; bí wọn bá sọ fun yín tabi ẹ gbọ́ nípa rẹ̀, ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí. Bí ó bá jẹ́ pé òtítọ́ ni, tí ìdánilójú sì wà pé ohun ìríra bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ ní Israẹli, ẹ mú ẹni tí ó ṣe ohun burúkú náà jáde lọ sí ẹnu ibodè yín, kí ẹ sì sọ ọ́ ní òkúta pa. Ẹlẹ́rìí gbọdọ̀ tó meji tabi mẹta kí wọ́n tó lè pa ẹnikẹ́ni fún irú ẹ̀sùn bẹ́ẹ̀, wọn kò gbọdọ̀ pa eniyan nítorí ẹ̀rí ẹnìkan ṣoṣo. Àwọn ẹlẹ́rìí ni wọ́n gbọdọ̀ kọ́kọ́ sọ òkúta lu ẹni náà, lẹ́yìn náà ni gbogbo eniyan yóo tó kó òkúta bò ó, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe yọ ẹni burúkú náà kúrò láàrin yín. “Bí ẹjọ́ kan bá ta kókó tí ó ní àríyànjiyàn ninu, tí ó sì ṣòro láti dá fún àwọn onídàájọ́ yín, kì báà jẹ mọ́ ṣíṣèèṣì paniyan ati mímọ̀ọ́nmọ̀ paniyan, tabi ẹ̀tọ́ lórí ohun ìní ẹni; tabi tí ẹnìkan bá ṣe ohun àbùkù kan sí ẹlòmíràn, ẹ óo lọ sí ibi tí OLUWA Ọlọrun yín yóo yàn, pé kí ẹ ti máa jọ́sìn. Ẹ tọ àwọn alufaa ọmọ Lefi lọ, kí ẹ sì kó ẹjọ́ yín lọ sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó wà ní ipò onídàájọ́ ní àkókò náà. Ẹ ro ẹjọ́ yín fún wọn, wọn yóo sì bá yín dá a. Ohunkohun tí wọ́n bá sọ fun yín ní ibi tí OLUWA bá yàn ni ẹ gbọdọ̀ ṣe. Ẹ gbọdọ̀ ṣọ́ra, kí ẹ sì ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá ní kí ẹ ṣe. Ẹjọ́ tí wọ́n bá dá fun yín ni kí ẹ gbà, kí ẹ sì tẹ̀lé gbogbo ìlànà tí wọ́n bá là sílẹ̀. Ẹ kò gbọdọ̀ yà sí ọ̀tún tabi sí òsì ninu ẹjọ́ tí wọ́n bá dá fun yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe oríkunkun sí ẹni tí ó jẹ́ onídàájọ́ nígbà náà, tabi alufaa tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ní àkókò náà, pípa ni kí ẹ pa á; bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe yọ ohun burúkú náà kúrò láàrin Israẹli. Gbogbo àwọn eniyan ni yóo gbọ́, ẹ̀rù yóo bà wọ́n; ẹnikẹ́ni kò sì ní ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́. “Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, tí ẹ bá gbà á, tí ẹ sì ń gbé inú rẹ̀, tí ẹ bá wí nígbà náà pé, ‘A óo fi ẹnìkan jọba lórí wa gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí wọ́n yí wa ká,’ ẹ lè fi ẹnikẹ́ni tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn fun yín jọba, ọ̀kan ninu àwọn arakunrin yín ni ẹ gbọdọ̀ fi jọba, ẹ kò gbọdọ̀ fi àlejò, tí kì í ṣe ọ̀kan ninu àwọn arakunrin yín jọba. Ṣugbọn kò gbọdọ̀ máa kó ẹṣin jọ fún ara rẹ̀ tabi kí ó mú kí àwọn eniyan náà pada lọ sí ilẹ̀ Ijipti láti ra ẹṣin kún ẹṣin, níwọ̀n ìgbà tí OLUWA ti wí fun yín pé, ‘Ẹ kò gbọdọ̀ pada lọ sí ibẹ̀ mọ́.’ Kò gbọdọ̀ kó aya jọ kí ọkàn rẹ̀ má baà yipada; bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ kó wúrà ati fadaka jọ fún ara rẹ̀. “Nígbà tí ó bá jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀, kí ó gba ìwé òfin yìí lọ́wọ́ àwọn alufaa ọmọ Lefi, kí ó dà á kọ sinu ìwé kan fún ara rẹ̀. Kí ẹ̀dà àwọn òfin yìí máa wà pẹlu rẹ̀, kí ó sì máa kà á ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀; kí ó lè kọ́ láti bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun rẹ̀, nípa pípa gbogbo òfin ati ìlànà wọnyi mọ́, kí ó sì máa tẹ̀lé wọn; kí ó má baà rò ninu ara rẹ̀ pé òun ga ju àwọn arakunrin òun lọ, kí ó má baà yipada sí ọ̀tún tabi sí òsì kúrò ninu òfin OLUWA, kí òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ lè pẹ́ lórí oyè ní Israẹli. “Gbogbo ẹ̀yà Lefi ni alufaa, nítorí náà wọn kò ní bá àwọn ẹ̀yà Israẹli yòókù pín ilẹ̀. Ninu ọrẹ fún ẹbọ sísun, ati àwọn ọrẹ mìíràn tí àwọn eniyan Israẹli bá mú wá fún OLUWA, ni àwọn ẹ̀yà Lefi yóo ti máa jẹ. Wọn kò ní ní ìpín láàrin àwọn arakunrin wọn. OLUWA ni ìpín tiwọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún wọn. “Ohun tí yóo jẹ́ ti àwọn alufaa lára ẹran tí àwọn eniyan bá fi rúbọ nìyí, kì báà jẹ́ akọ mààlúù tabi aguntan ni wọ́n wá fi rúbọ, wọn yóo fún alufaa ní apá ati ẹ̀rẹ̀kẹ́ mejeeji, ati àpòlùkú rẹ̀. Kí ẹ fún àwọn alufaa ní àkọ́so oko yín, ati àkọ́pọn ọtí waini yín, ati àkọ́ṣe òróró yín, ati irun aguntan tí ẹ bá kọ́kọ́ rẹ́. Nítorí ninu gbogbo ẹ̀yà Israẹli, ẹ̀yà Lefi ati ti arọmọdọmọ wọn ni OLUWA Ọlọrun yín ti yàn láti máa ṣe iṣẹ́ alufaa fún un. “Bí ọ̀kan ninu ẹ̀yà Lefi bá dìde láti ilé rẹ̀, tabi ibikíbi tí ó wù kí ó ti wá ní Israẹli, tabi ìgbà yòówù tí ó bá fẹ́ láti wá sí ibi tí OLUWA ti yàn fún ìsìn rẹ̀, ó lè ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Lefi ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yòókù, tí wọn ń ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn níbẹ̀ níwájú OLUWA. Bákan náà ni wọn yóo jọ pín oúnjẹ wọn láìka ohun tí àwọn ará ilé rẹ̀ bá fi ranṣẹ sí i gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó kàn án ninu ogún baba rẹ̀ tí wọ́n tà. “Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, ẹ kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ìwà ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè náà ń hù. Ẹnikẹ́ni ninu yín kò gbọdọ̀ fi ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ sísun, kì báà ṣe ọmọ rẹ̀ obinrin tabi ọkunrin. Ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ máa wo iṣẹ́ kiri tabi kí ó di aláfọ̀ṣẹ tabi oṣó; tabi kí ó máa sa òògùn sí ẹlòmíràn, tabi kí ó máa bá àwọn àǹjọ̀nú sọ̀rọ̀, tabi kí ó di abókùúsọ̀rọ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àwọn nǹkan tí a dárúkọ wọnyi di ohun ìríra níwájú OLUWA, ati pé nítorí ohun ìríra wọnyi ni OLUWA Ọlọrun yín ṣe ń lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde fun yín. Gbogbo ìwà ati ìṣe yín níláti jẹ́ èyí tí ó tọ́ níwájú OLUWA Ọlọrun yín. “Àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ óo gba ilẹ̀ wọn yìí a máa ṣe àyẹ̀wò, wọn a sì máa gbọ́ ti àwọn aláfọ̀ṣẹ, ṣugbọn ní tiyín, OLUWA Ọlọrun yín kò gbà fun yín pé kí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀. OLUWA Ọlọrun yín yóo gbé wolii kan dìde tí yóo dàbí mi láàrin yín, tí yóo jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn arakunrin yín, òun ni kí ẹ máa gbọ́ràn sí lẹ́nu. “Bíi ti ọjọ́ tí ẹ péjọ ní òkè Horebu tí ẹ bẹ OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ sọ fún mi pé, ‘Má jẹ́ kí á gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun wa mọ́, tabi kí á rí iná ńlá yìí mọ́; kí á má baà kú.’ OLUWA wí fún mi nígbà náà pé, ‘Gbogbo ohun tí wọ́n sọ patapata ni ó dára. N óo gbé wolii kan dìde gẹ́gẹ́ bíì rẹ, láàrin àwọn arakunrin wọn, n óo fi ọ̀rọ̀ mi sí i lẹ́nu, yóo sì máa sọ ohun gbogbo tí mo bá pa láṣẹ fún wọn. Ẹnikẹ́ni tí kò bá gba ọ̀rọ̀ mi, tí yóo máa sọ ní orúkọ mi, èmi fúnra mi ni n óo jẹ olúwarẹ̀ níyà. Ṣugbọn wolii tí ó bá fi orúkọ mi jẹ́ iṣẹ́ tí n kò rán an, tabi tí ó jẹ́ iṣẹ́ kan fun yín ní orúkọ àwọn oriṣa, wolii náà gbọdọ̀ kú ni.’ “Bí ẹ bá ń rò ninu ọkàn yín pé, báwo ni ẹ óo ti ṣe mọ ìgbà tí wolii kan bá ń jẹ́ iṣẹ́ tí Ọlọrun kò rán an. Nígbà tí wolii kan bá jíṣẹ́ ní orúkọ OLUWA, bí ohun tí ó sọ pé yóo ṣẹlẹ̀ kò bá ṣẹlẹ̀, a jẹ́ pé kì í ṣe OLUWA ni ó rán an; wolii náà ń dá iṣẹ́ ara rẹ̀ jẹ́ ni, ẹ má bẹ̀rù rẹ̀. “Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá pa àwọn orílẹ̀-èdè tí yóo fun yín ní ilẹ̀ wọn run, tí ẹ bá gba ilẹ̀ wọn, tí ẹ sì ń gbé inú àwọn ìlú wọn, ati ilé wọn, ẹ ya ìlú mẹta sọ́tọ̀ fún ara yín ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín. Ẹ pín ilẹ̀ náà sí agbègbè mẹta, kí ẹ sì la ọ̀nà mẹta wọ inú àwọn ìlú náà. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ìlú mẹtẹẹta tí ẹ yà sọ́tọ̀ gbọdọ̀ wà ní agbègbè kọ̀ọ̀kan. Ẹ óo sì ṣí àwọn ọ̀nà tí ó wọ ìlú wọnyi kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì paniyan lè tètè sálọ sibẹ. Èyí wà fún anfaani ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì paniyan. Bí ẹnìkan bá ṣèèṣì pa aládùúgbò rẹ̀ láìjẹ́ pé wọ́n ti ń bá ara wọn ṣe ọ̀tá tẹ́lẹ̀, bí ó bá sálọ sí èyíkéyìí ninu àwọn ìlú náà, yóo gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là. Bí àpẹẹrẹ, bí ẹnìkan bá lọ sinu igbó pẹlu aládùúgbò rẹ̀ láti gé igi, bí ó ti ń fi àáké gé igi lọ́wọ́, bí irin àáké náà bá yọ, tí ó lọ bá aládùúgbò rẹ̀, tí ó sì pa á; irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè sálọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú náà, kí ó sì gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là. Kí ó má jẹ́ pé, nígbà tí ẹni tí yóo gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó ṣèèṣì pa bá ń lé e lọ pẹlu ibinu, bí ibi tí yóo sá àsálà lọ bá jìnnà jù, yóo bá a, yóo sì pa á; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò yẹ kí wọ́n pa ẹni tí ó ṣèèṣì paniyan yìí, níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé òun ati aládùúgbò rẹ̀ kìí ṣe ọ̀tá tẹ́lẹ̀. Nítorí náà ni mo fi pàṣẹ fun yín pé, ẹ níláti ya ìlú mẹta sọ́tọ̀. “Bí OLUWA Ọlọrun yín bá sì mú kí ilẹ̀ yín tóbi síi gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún àwọn baba yín, tí ó bá fun yín ní gbogbo ilẹ̀ tí ó ṣèlérí fún àwọn baba yín, bí ẹ bá lè pa gbogbo òfin rẹ̀ tí mo fun yín lónìí mọ́, tí ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀, nígbà náà, ẹ tún fi ìlú mẹta mìíràn kún àwọn ìlú mẹta ti àkọ́kọ́. Kí ẹnikẹ́ni má baà ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín láti jogún, kí ẹ̀bi ìtàjẹ̀sílẹ̀ má baà wà lórí yín. “Ṣugbọn bí ẹnikẹ́ni bá kórìíra aládùúgbò rẹ̀, tí ó bá ba dè é, tí ó mọ̀ọ́nmọ̀ pa á, tí ó sì sálọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú wọnyi, kí àwọn àgbààgbà ìlú rán ni lọ mú ẹni náà wá, kí wọ́n sì fi lé ẹni tí yóo gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó pa lọ́wọ́, kí ó lè pa ẹni tí ó mọ̀ọ́nmọ̀ paniyan yìí. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣàánú rẹ̀ rárá, ṣugbọn ẹ níláti mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kúrò láàrin Israẹli, kí ó lè dára fun yín. “Ninu ogún tìrẹ tí ó bá kàn ọ́ ninu ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín láti gbà, o kò gbọdọ̀ sún ohun tí àwọn baba ńlá rẹ bá fi pààlà ilẹ̀. “Ẹ̀rí ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo péré kò tó láti fi dá ẹnikẹ́ni lẹ́bi lórí ẹ̀sùnkẹ́sùn tí wọ́n bá fi kàn án, tabi ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ tí ó bá ṣẹ̀. Ẹlẹ́rìí gbọdọ̀ tó meji tabi mẹta, kí ẹ tó lè dá ẹnikẹ́ni lẹ́bi lórí ẹ̀sùn kan. Bí ẹlẹ́rìí èké kan bá dìde láti jẹ́rìí èké mọ́ ẹnìkan, tí ó bá fi ẹ̀sùn kàn án pé ó ṣe nǹkan burúkú, kí àwọn mejeeji tí wọn ń ṣe àríyànjiyàn yìí wá siwaju OLUWA, níwájú àwọn alufaa ati àwọn tí wọ́n jẹ́ onídàájọ́ nígbà náà. Kí àwọn onídàájọ́ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí bí ọ̀rọ̀ ti rí, bí wọ́n bá rí i pé ẹ̀rí èké ni ọkunrin yìí ń jẹ́, tabi pé ẹ̀sùn èké ni ó fi kan arakunrin rẹ̀; ohun tí ó fẹ́ kí wọ́n ṣe fún arakunrin rẹ̀ gan an ni kí ẹ ṣe fún òun náà. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú nǹkan burúkú kúrò láàrin yín. Àwọn yòókù yóo gbọ́, ẹ̀rù yóo bà wọ́n, wọn kò sì ní ṣe irú nǹkan burúkú bẹ́ẹ̀ mọ́ láàrin yín. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣàánú olúwarẹ̀ rárá, tó bá jẹ́ pé ó fẹ́ kí wọ́n pa arakunrin rẹ̀ ni, pípa ni kí ẹ pa òun náà; bí ó bá jẹ́ ẹyinjú tabi eyín rẹ̀ ni ó fẹ́ kí wọ́n yọ, ẹ yọ ojú tabi eyín ti òun náà; bí ó bá sì jẹ́ pé ọwọ́ tabi ẹsẹ̀ rẹ̀ ni ó fẹ́ kí wọ́n gé, ẹ gé ọwọ́ tabi ẹsẹ̀ ti òun náà. “Nígbà tí ẹ bá jáde lọ láti bá àwọn ọ̀tá yín jà, tí ẹ bá rí ọpọlọpọ ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ọmọ ogun tí wọ́n pọ̀ jù yín lọ, ẹ kò gbọdọ̀ bẹ̀rù wọn, nítorí OLUWA Ọlọrun yín, tí ó kó yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti wà pẹlu yín. Nígbà tí ẹ bá súnmọ́ ojú ogun, kí alufaa jáde kí ó sì bá àwọn eniyan náà sọ̀rọ̀, kí ó wí fún wọn pé, ‘Ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan Israẹli, tí ẹ̀ ń lọ sí ojú ogun lónìí láti bá àwọn ọ̀tá yín jà, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí àyà yín já, ẹ̀rù kò sì gbọdọ̀ bà yín, ẹ kò gbọdọ̀ wárìrì tabi kí ẹ jẹ́ kí jìnnìjìnnì dà bò yín. Nítorí OLUWA Ọlọrun yín ń ba yín lọ láti bá àwọn ọ̀tá yín jà, ati láti fun yín ní ìṣẹ́gun.’ “Lẹ́yìn náà, àwọn ọ̀gágun yóo wí fún àwọn eniyan náà pé, ‘Ǹjẹ́ ọkunrin kan wà ninu yín tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ ilé titun, tí kò tíì yà á sí mímọ́? Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ ya ilé rẹ̀ sí mímọ́, kí ó má baà jẹ́ pé bí ó bá kú sí ogun, ẹlòmíràn ni yóo ya ilé rẹ̀ sí mímọ́. Ǹjẹ́ ọkunrin kan wà ninu yín tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbin ọgbà àjàrà, tí kò sì tíì jẹ ninu èso rẹ̀? Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ pada sí ilé rẹ̀, kí ó má baà jẹ́ pé bí ó bá kú sí ogun, ẹlòmíràn ni yóo jẹ èso ọgbà àjàrà rẹ̀. Ǹjẹ́ ọkunrin kan wà ninu yín tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ iyawo sọ́nà tí kò tíì gbé e wọlé? Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ pada lọ sí ilé rẹ̀, kí ó má baà jẹ́ pé bí ó bá kú sí ogun, ẹlòmíràn ni yóo fẹ́ iyawo rẹ̀.’ “Àwọn ọ̀gágun yóo tún bá àwọn eniyan náà sọ̀rọ̀ pé, ‘Ǹjẹ́ ọkunrin kan wà ninu yín tí ẹ̀rù ń bà, tabi tí àyà rẹ̀ ń já? Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ pada sí ilé, kí ó má baà kó ojora bá àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀.’ Nígbà tí àwọn ọ̀gágun bá parí ọ̀rọ̀ tí wọn ń bá àwọn eniyan náà sọ, wọn óo yan àwọn kan tí wọn óo máa ṣe aṣaaju ìsọ̀rí-ìsọ̀rí àwọn jagunjagun. “Bí ẹ bá ti súnmọ́ ìlú tí ẹ fẹ́ bá jagun, ẹ kọ́ rán iṣẹ́ alaafia sí wọn. Bí wọ́n bá rán iṣẹ́ alaafia pada, tí wọ́n sì ṣí ìlẹ̀kùn wọn fun yín, kí ẹ kó gbogbo àwọn ará ìlú náà lẹ́rú kí wọ́n sì máa sìn yín. Ṣugbọn bí wọ́n bá kọ̀, tí àwọn náà dìde ogun si yín, ẹ dó ti ìlú náà. Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá fi ìlú náà le yín lọ́wọ́, kí ẹ fi idà pa gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n wà níbẹ̀. Ṣugbọn kí ẹ dá àwọn obinrin ati àwọn ọmọ wọn sí, ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, ati gbogbo dúkìá yòókù tí ó wà ninu ìlú náà, kí ẹ kó gbogbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìkógun fún ara yín, kí ẹ máa lo gbogbo dúkìá àwọn ọ̀tá yín tí OLUWA Ọlọrun yín ti fun yín. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe sí àwọn ìlú tí ó jìnnà sí yín, tí kì í ṣe àwọn ìlú orílẹ̀-èdè tí ó wà níhìn-ín. “Ṣugbọn gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ninu àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fi fun yín, gẹ́gẹ́ bí ìní yín, ẹ kò gbọdọ̀ dá ohun alààyè kan sí ninu wọn. Rírun ni kí ẹ run gbogbo wọn patapata, gbogbo àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Amori, ati àwọn ará Kenaani, ati àwọn ará Perisi, ati àwọn ará Hifi, ati àwọn ará Jebusi; gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun yín ti pa á láṣẹ. Kí wọ́n má baà kọ yín ní ìkọ́kúkọ̀ọ́, kí ẹ má baà máa ṣe oríṣìíríṣìí àwọn ohun ìríra tí wọn ń ṣe nígbà tí wọ́n bá ń bọ àwọn oriṣa wọn, kí ẹ má baà dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun yín. “Nígbà tí ẹ bá dó ti ìlú kan fún ìgbà pípẹ́, tí ẹ bá ń bá ìlú náà jagun tí ẹ fẹ́ gbà á, ẹ kò gbọdọ̀ bẹ́ àwọn igi eléso wọn lulẹ̀ ní ìbẹ́kúbẹ̀ẹ́. Jíjẹ ni kí ẹ máa jẹ èso igi wọn, ẹ kò gbọdọ̀ gé wọn lulẹ̀. Àbí eniyan ni igi inú igbó, tí ẹ óo fi máa gbé ogun tì í? Àwọn igi tí ẹ bá mọ̀ pé èso wọn kìí ṣe jíjẹ nìkan ni kí ẹ máa gé, kí ẹ máa fi ṣe àtẹ̀gùn, tí ẹ fi lè wọ ìlú náà, títí tí ọwọ́ yín yóo fi tẹ̀ ẹ́. “Bí ẹ bá rí òkú eniyan tí wọ́n pa sinu igbó, lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, tí ẹ kò sì mọ ẹni tí ó pa á, kí àwọn àgbààgbà ati àwọn adájọ́ yín jáde wá, kí wọ́n wọn ilẹ̀ láti ibi tí wọ́n pa ẹni náà sí títí dé gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní àyíká ibẹ̀. Kí àwọn àgbààgbà ìlú tí ó bá súnmọ́ ibẹ̀ jùlọ wá ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan tí ẹnikẹ́ni kò tíì so àjàgà mọ́ lọ́rùn láti fi ṣiṣẹ́ rí, kí wọ́n mú ọ̀dọ́ akọ mààlúù náà lọ sí àfonífojì tí ó ní odò tí ń ṣàn, tí ẹnikẹ́ni kò gbin ohunkohun sí rí, kí wọ́n sì lọ́ ọ̀dọ́ mààlúù náà lọ́rùn pa níbẹ̀. Kí àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, bá wọn lọ pẹlu; nítorí àwọn ni OLUWA Ọlọrun yín yàn láti máa ṣe alufaa ati láti máa súre fún àwọn eniyan ní orúkọ OLUWA; ati pé àwọn ni OLUWA Ọlọrun yàn láti parí àríyànjiyàn ati ẹjọ́. Kí gbogbo àwọn àgbààgbà tí wọ́n wà ní ìlú náà wẹ ọwọ́ wọn sórí mààlúù tí wọ́n ti lọ́ lọ́rùn pa yìí. Kí wọ́n wí pé, ‘A kò lọ́wọ́ ninu ikú ọkunrin yìí, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì mọ ẹni tí ó pa á. OLUWA, dáríjì Israẹli, àwọn eniyan rẹ, tí o ti rà pada, má sì ṣe jẹ àwọn eniyan Israẹli níyà nítorí ikú aláìṣẹ̀ yìí. Ṣugbọn dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ìtàjẹ̀sílẹ̀ náà jì wọ́n.’ Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe wẹ ara yín mọ́ kúrò ninu ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀, bí ẹ bá ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA. “Nígbà tí ẹ bá lọ bá àwọn ọ̀tá yín jagun, tí OLUWA Ọlọrun yín bá fi wọ́n le yín lọ́wọ́, tí ẹ bá sì kó wọn lẹ́rú; tí ẹ bá rí arẹwà obinrin kan láàrin àwọn ẹrú náà tí ó wù yín láti fi ṣe aya fún ara yín. Ẹ mú un wá sí ilẹ̀ yín ẹ fá irun orí rẹ̀, kí ẹ sì gé èékánná ọwọ́ rẹ̀. Ẹ bọ́ aṣọ ẹrú rẹ̀ sílẹ̀, kí ó wà ní ilẹ̀ yín, kí ó sì máa ṣọ̀fọ̀ baba ati ìyá rẹ̀ fún odidi oṣù kan. Lẹ́yìn náà ẹ lè wọlé tọ̀ ọ́, kí ẹ sì di tọkọtaya. Lẹ́yìn náà, tí kò bá wù yín mọ́ ẹ níláti fún un láyè kí ó lọ sí ibikíbi tí ó bá wù ú, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ tà á bí ẹrú, ẹ kò sì gbọdọ̀ lò ó ní ìlò ẹrú, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti bá a lòpọ̀ rí. “Bí ẹnìkan bá ní iyawo meji, tí ó fẹ́ràn ọ̀kan, tí kò sì fẹ́ràn ekeji, tí àwọn mejeeji bímọ fún un, tí ó bá jẹ́ pé iyawo tí kò fẹ́ràn ni ó bí àkọ́bí ọmọkunrin rẹ̀ fún un, ní ọjọ́ tí yóo bá ṣe ètò bí àwọn ọmọ rẹ̀ yóo ṣe pín ogún rẹ̀, kò gbọdọ̀ ṣe ojuṣaaju, kí ó pín ogún fún ọmọ ẹni tí ó fẹ́ràn gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí, kí ó sì ṣe ọmọ ẹni tí kò fẹ́ràn bí ẹni pé kì í ṣe òun ni àkọ́bí rẹ̀. Ṣugbọn kí ó fihàn pé ọmọ obinrin tí òun kò fẹ́ràn yìí ni àkọ́bí òun, kí ó sì fún un ní ogún tí ó tọ́ sí i ninu ohun ìní rẹ̀. Òun ṣá ni àkọ́bí rẹ̀, òun sì ni ẹ̀tọ́ àkọ́bí tọ́ sí. “Bí ẹnìkan bá bí ọmọkunrin kan, tí ó jẹ́ aláìgbọràn ati olórí kunkun ọmọ, tí kì í gbọ́, tí kì í sì í gba ti àwọn òbí rẹ̀, tí wọ́n bá a wí títí, ṣugbọn tí kò gbọ́, kí baba ati ìyá rẹ̀ mú un wá siwaju àwọn àgbààgbà ìlú náà, ní ẹnu bodè ìlú tí ó ń gbé, kí wọ́n wí fún àwọn àgbààgbà ìlú náà pé, ‘Ọmọ wa yìí ya olóríkunkun ati aláìgbọràn, kì í gbọ́rọ̀ sí wa lẹ́nu. Oníjẹkújẹ ati onímukúmu sì ni.’ Lẹ́yìn náà kí àwọn ọkunrin ìlú sọ ọ́ ní òkúta pa. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ ó ṣe yọ ibi kúrò láàrin yín; gbogbo Israẹli yóo gbọ́, wọn yóo sì bẹ̀rù. “Bí ẹnìkan bá dẹ́ṣẹ̀ kan, tí ó jẹ́ pé ikú ni ìjìyà irú ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, tí ẹ bá so ó kọ́ sórí igi, òkú rẹ̀ kò gbọdọ̀ sun orí igi náà. Ẹ níláti sin ín ní ọjọ́ náà, nítorí ẹni ìfibú Ọlọrun ni ẹni tí a bá so kọ́ orí igi, ẹ kò gbọdọ̀ sọ ilẹ̀ yín tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín di aláìmọ́. “Ẹ kò gbọdọ̀ máa wo mààlúù tabi aguntan arakunrin yín, kí ó máa ṣìnà lọ, kí ẹ sì mójú kúrò, ẹ níláti fà á tọ olówó rẹ̀ lọ. Bí ibi tí olówó ẹran ọ̀sìn yìí ń gbé bá jìnnà jù, tabi tí ẹ kò bá mọ ẹni náà, ẹ níláti fa ẹran ọ̀sìn náà wálé, kí ó sì wà lọ́dọ̀ yín títí tí olówó rẹ̀ yóo fi máa wá a kiri. Nígbà tí ó bá ń wá a, ẹ níláti dá a pada fún un. Bákan náà ni ẹ níláti ṣe, tí ó bá jẹ́ pé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ni ó sọnù, tabi aṣọ rẹ̀, tabi ohunkohun tí ó bá jẹ́ ti arakunrin yín, tí ó bá sọnù tí ẹ sì rí i. Ẹ kò gbọdọ̀ mójú kúrò bí ẹni pé ẹ kò rí i. “Ẹ kò gbọdọ̀ máa wo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tabi akọ mààlúù arakunrin yín, tí ó wó lulẹ̀ lẹ́bàá ọ̀nà, kí ẹ sì mójú kúrò bí ẹni pé ẹ kò rí i. Ẹ níláti ràn án lọ́wọ́ láti gbé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tabi akọ mààlúù rẹ̀ dìde. “Obinrin kò gbọdọ̀ wọ aṣọkáṣọ tí ó bá jẹ́ ti ọkunrin, bẹ́ẹ̀ sì ni ọkunrin kò gbọdọ̀ wọ aṣọkáṣọ tí ó bá jẹ́ ti obinrin nítorí pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìríra ni ó jẹ́ lójú OLUWA Ọlọrun yín. “Bí ẹ bá rí ìtẹ́ ẹyẹ lórí igi tabi ní ilẹ̀, tí ẹyin tabi ọmọ bá wà ninu rẹ̀, tí ìyá ẹyẹ yìí bá ràdọ̀ bò wọ́n, tabi tí ó bá sàba lé ẹyin rẹ̀, ẹ kò gbọdọ̀ kó àwọn ọmọ ẹyẹ náà pẹlu ìyá wọn. Ẹ níláti fi ìyá wọn sílẹ̀ kí ó máa lọ ṣugbọn ẹ lè kó àwọn ọmọ rẹ̀, kí ó lè dára fun yín, kí ẹ sì lè pẹ́ láyé. “Tí ẹ bá kọ́ ilé titun, ẹ níláti ṣe ìgbátí sí òrùlé rẹ̀ yípo, kí ẹ má baà wá di ẹlẹ́bi bí ẹnikẹ́ni bá jábọ́ láti orí òrùlé yín, tí ó sì kú. “Ẹ kò gbọdọ̀ gbin ohunkohun sáàrin àwọn àjàrà tí ẹ bá gbìn sinu ọgbà àjàrà yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àjàrà náà, ati ohun tí ẹ gbìn sáàrin rẹ̀ yóo di ti ibi mímọ́. “Ẹ kò gbọdọ̀ so àjàgà kan náà mọ́ akọ mààlúù ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ lọ́rùn, láti fi wọ́n ṣiṣẹ́ ninu oko. “Ẹ kò gbọdọ̀ wọ aṣọkáṣọ tí wọ́n bá pa irun pọ̀ mọ́ òwú hun. “Ẹ gbọdọ̀ fi oko wọnjanwọnjan sí igun mẹrẹẹrin aṣọ ìbora yín. “Bí ẹnìkan bá gbé ọmọge níyàwó, ṣugbọn tí ó kórìíra rẹ̀ lẹ́yìn tí ó ti bá a lòpọ̀, tí ó wá sọ pé ó ti ṣe ìṣekúṣe, tí ó sì fi bẹ́ẹ̀ sọ ọ́ ní orúkọ burúkú, tí ó bá wí pé, ‘Mo gbé obinrin yìí níyàwó ṣugbọn nígbà tí mo súnmọ́ ọn, n kò bá a nílé.’ “Kí baba ati ìyá ọmọbinrin yìí mú aṣọ ìbálé rẹ̀ jáde, kí wọ́n sì mú un tọ àwọn àgbààgbà ìlú náà lọ ní ẹnubodè. Kí baba ọmọ náà wí fún wọn pé, ‘Mo fi ọmọbinrin mi yìí fún ọkunrin yìí ní aya, lẹ́yìn tí ó ti bá a lòpọ̀ tán, ó fi ẹ̀sùn kàn án pé ó ti ṣe ìṣekúṣe. Ó ní, “N kò bá ọmọ rẹ nílé.” ’ Kí baba ọmọbinrin tẹ́ aṣọ ìbálé rẹ̀ sílẹ̀ níwájú àwọn àgbààgbà, kí ó sì wí pé, ‘Èyí ni ẹ̀rí pé ó bá ọmọ mi nílé.’ Àwọn àgbààgbà ìlú náà yóo mú ọkunrin yìí, wọn yóo nà án dáradára. Wọn yóo sì gba ọgọrun-un ìwọ̀n ṣekeli fadaka lọ́wọ́ rẹ̀ fún baba ọmọbinrin náà bíi owó ìtanràn; nítorí pé ó ti bá ọ̀kan ninu àwọn ọmọbinrin Israẹli lórúkọ jẹ́. Obinrin náà yóo sì tún jẹ́ iyawo rẹ̀, kò sì gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. “Ṣugbọn bí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan obinrin náà bá jẹ́ òtítọ́, pé wọn kò bá a nílé, Wọn yóo fa obinrin náà lọ sí ẹnu ọ̀nà ilé baba rẹ̀, àwọn ọkunrin ìlú yóo sì sọ ọ́ ní òkúta pa, nítorí pé ó ti hu ìwà òmùgọ̀ ní Israẹli níti pé ó ṣe àgbèrè ní ilé baba rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú ibi yìí kúrò láàrin yín. “Bí ọwọ́ bá tẹ ọkunrin kan ní ibi tí ó ti ń bá iyawo oníyàwó lòpọ̀, pípa ni ẹ gbọdọ̀ pa àwọn mejeeji; ati ọkunrin ati obinrin náà. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú ibi yìí kúrò láàrin yín. “Bí ẹnìkan bá rí ọmọge kan, tí ó jẹ́ àfẹ́sọ́nà láàrin ìlú, tí ó sì bá a lòpọ̀, ẹ mú àwọn mejeeji jáde wá sí ẹnubodè ìlú, kí ẹ sì sọ wọ́n ní òkúta pa. Ẹ̀ṣẹ̀ ti obinrin ni pé, nígbà tí wọ́n kì í mọ́lẹ̀ láàrin ìlú, kò pariwo kí aládùúgbò gbọ́. Ẹ̀ṣẹ̀ ti ọkunrin ni pé, ó ba àfẹ́sọ́nà arakunrin rẹ̀ jẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú ibi yìí kúrò láàrin yín. “Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé ninu igbó ni ọkunrin kan ti ki ọmọbinrin kan tí ó jẹ́ àfẹ́sọ́nà ẹnìkan mọ́lẹ̀, tí ó sì bá a lòpọ̀, ọkunrin nìkan ni kí wọ́n pa. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ohunkohun sí ọmọbinrin náà, kò jẹ̀bi ikú rárá, nítorí ọ̀rọ̀ náà dàbí pé kí ọkunrin kan pàdé aládùúgbò rẹ̀ kan lójú ọ̀nà, kí ó sì lù ú pa. Nítorí pé, inú igbó ni ó ti kì í mọ́lẹ̀. Bí ọmọbinrin àfẹ́sọ́nà yìí tilẹ̀ ké: ‘Gbà mí! Gbà mí!’ Kò sí ẹnikẹ́ni nítòsí tí ó lè gbà á sílẹ̀. “Bí ọkunrin kan bá rí ọmọbinrin kan, tí kì í ṣe àfẹ́sọ́nà ẹnikẹ́ni, tí ó kì í mọ́lẹ̀, tí ó sì bá a lòpọ̀, bí ọwọ́ bá tẹ̀ wọ́n, ọkunrin tí ó bá obinrin yìí lòpọ̀ níláti fún baba ọmọbinrin náà ní aadọta ìwọ̀n ṣekeli fadaka. Ọmọbinrin yìí yóo sì di iyawo rẹ̀, nítorí pé ó ti fi ipá bá a lòpọ̀, kò sì gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. “Ọkunrin kò gbọdọ̀ fi èyíkéyìí ninu àwọn aya baba rẹ̀ ṣe aya, tabi kí ó bá a lòpọ̀. “Ọkunrin tí wọ́n bá tẹ̀ lọ́dàá, tabi tí wọ́n bá gé nǹkan ọkunrin rẹ̀, kò gbọdọ̀ bá ìjọ eniyan OLUWA péjọ. “Ọmọ àlè kankan kò gbọdọ̀ bá ìjọ eniyan OLUWA péjọ, arọmọdọmọ rẹ̀ títí dé ìran kẹwaa kò gbọdọ̀ bá ìjọ eniyan OLUWA péjọ. “Ará Amoni ati Moabu kankan kò gbọdọ̀ bá ìjọ eniyan OLUWA péjọ, arọmọdọmọ wọn títí dé ìran kẹwaa kò gbọdọ̀ bá ìjọ eniyan OLUWA péjọ; nítorí pé, nígbà tí ẹ̀ ń bọ̀ láti ilẹ̀ Ijipti, wọn kò gbé oúnjẹ ati omi pàdé yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, Balaamu ọmọ Beori ará Petori, ní Mesopotamia, ni wọ́n bẹ̀ pé kí ó wá gbé yín ṣépè. Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun yín kò fetí sí ti Balaamu, ó yí èpè náà sí ìre fun yín nítorí pé ó fẹ́ràn yín. Ẹ kò gbọdọ̀ ro ire kàn wọ́n tabi kí ẹ wá ìtẹ̀síwájú wọn títí lae. “Ẹ kò gbọdọ̀ kórìíra àwọn ọmọ Edomu, nítorí pé arakunrin yín ni wọ́n. Ẹ kò gbọdọ̀ kórìíra àwọn ará Ijipti nítorí pé ẹ ti ṣe àtìpó ní ilẹ̀ wọn rí. Bẹ̀rẹ̀ láti ìran kẹta wọn, wọ́n lè bá ìjọ eniyan OLUWA péjọ. “Nígbà tí ẹ bá jáde lọ láti bá àwọn ọ̀tá yín jagun, tí ẹ bá sì wà ninu àgọ́, ẹ níláti yẹra fún ohunkohun tíí ṣe ibi. Bí ọkunrin kan bá wà ninu yín tí ó di aláìmọ́ nítorí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i láàrin òru, kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ jáde kúrò ninu àgọ́. Kò gbọdọ̀ wọ inú àgọ́ wá mọ́. Ṣugbọn nígbà tí ó bá di ìrọ̀lẹ́, kí ó wẹ̀. Nígbà tí oòrùn bá sì wọ̀, ó lè wọ inú àgọ́ wá. “Ẹ gbọdọ̀ ní ibìkan lẹ́yìn àgọ́ tí ẹ óo máa yàgbẹ́ sí. Kí olukuluku yín ní ọ̀pá kan, tí yóo máa dì mọ́ ara ohun ìjà rẹ̀, tí ó lè fi gbẹ́lẹ̀ nígbà tí ó bá fẹ́ yàgbẹ́; nígbà tí ó bá sì yàgbẹ́ tán, ọ̀pá yìí ni yóo fi wa erùpẹ̀ bò ó mọ́lẹ̀. Nítorí pé, OLUWA Ọlọrun yín wà pẹlu yín ninu àgọ́ láti gbà yín là, ati láti jẹ́ kí ọwọ́ yín tẹ àwọn ọ̀tá yín. Nítorí náà, àgọ́ yín níláti jẹ́ mímọ́, kí OLUWA má baà rí ohunkohun tí ó jẹ́ àìmọ́ láàrin yín, kí ó sì yipada kúrò lọ́dọ̀ yín. “Bí ẹrú kan bá sá kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀, tí ó bá tọ̀ yín wá, ẹ kò gbọdọ̀ lé e pada sọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀. Ẹ jẹ́ kí ó máa bá yín gbé, kí ó wà láàrin yín ninu èyíkéyìí tí ó bá yàn ninu àwọn ìlú yín. Ibi tí ó bá wù ú ni ó lè gbé, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ni ín lára. “Ẹnikẹ́ni ninu àwọn eniyan Israẹli, kì báà jẹ́ ọkunrin tabi obinrin, kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di alágbèrè ní ilé oriṣa kankan. Ọkunrin tabi obinrin kankan kò gbọdọ̀ mú owó tí ó bá gbà ní ibi àgbèrè ṣíṣe wá sinu ilé OLUWA láti san ẹ̀jẹ́kẹ́jẹ̀ẹ́ tí ó bá jẹ́, nítorí pé, àgbèrè ṣíṣe jẹ́ ohun ìríra níwájú OLUWA Ọlọrun yín. “Tí ẹ̀yin ọmọ Israẹli bá yá ara yín lówó, tabi oúnjẹ tabi ohunkohun, ẹ kò gbọdọ̀ gba èlé lórí rẹ̀. Bí ẹ bá yá àlejò ní nǹkan, ẹ lè gba èlé, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ yá arakunrin yín ní ohunkohun kí ẹ sì gba èlé, kí OLUWA Ọlọrun yín lè bukun yín ninu ohun gbogbo tí ẹ bá dáwọ́lé ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ láti gbà. “Nígbà tí ẹ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun yín, ẹ kò gbọdọ̀ má san ẹ̀jẹ́ náà, nítorí OLUWA Ọlọrun yín yóo bèèrè rẹ̀ lọ́wọ́ yín, yóo sì di ẹ̀ṣẹ̀ sí yín lọ́rùn bí ẹ kò bá san án. Ṣugbọn tí ẹ kò bá jẹ́jẹ̀ẹ́ rárá, kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ fun yín. Níwọ̀n ìgbà tí ẹ bá ti fínnúfẹ́dọ̀ jẹ́jẹ̀ẹ́ ohunkohun fún OLUWA Ọlọrun yín, ẹ ti fi ẹnu yín ṣèlérí, ẹ sì níláti rí i pé, ẹ mú ẹ̀jẹ́ náà ṣẹ. “Nígbà tí ẹ bá ń kọjá lọ ní ibi ọgbà àjàrà ẹlòmíràn, ẹ lè jẹ ìwọ̀nba èso àjàrà tí ó bá tẹ́ yín lọ́rùn, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ mú ẹyọkan lọ́wọ́ lọ. Nígbà tí ẹ bá ń kọjá lọ ní oko ọkà ẹlòmíràn, tí wọn kò tíì kórè, ẹ lè fi ọwọ́ ya ìwọ̀nba tí ẹ lè jẹ, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ fi dòjé gé ọkà ọlọ́kà. “Bí ọkunrin kan bá fẹ́ iyawo, tí iyawo náà kò bá wù ú mọ́ nítorí pé ó rí ohun àléébù kan ninu ìwà rẹ̀ tí kò tẹ́ ẹ lọ́rùn; tí ó bá já ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún un, tí obinrin náà jáde kúrò ní ilé rẹ̀, tí obinrin náà sì bá tirẹ̀ lọ; bí obinrin yìí bá lọ ní ọkọ mìíràn, ṣugbọn tí kò tún wu ọkọ titun náà, tí òun náà tún já ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún un, tí ó sì tún tì í jáde kúrò ninu ilé rẹ̀, tabi tí ọkọ keji tí obinrin yìí fẹ́ bá kú, ọkọ rẹ̀ àkọ́kọ́ kò gbọdọ̀ gbà á pada mọ́ nítorí pé obinrin náà ti di aláìmọ́. Ohun ìríra ni èyí lójú OLUWA. Ẹ kò gbọdọ̀ dá irú ẹ̀ṣẹ̀ yìí ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín. “Bí ọkunrin kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gbeyawo, kò gbọdọ̀ jáde lọ sí ojú ogun tabi kí á fún un ní iṣẹ́ ìlú ṣe, ó gbọdọ̀ wà ní òmìnira ninu ilé rẹ̀ fún ọdún kan gbáko, kí ó máa faramọ́ iyawo rẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́. “Bí ẹnikẹ́ni bá yá eniyan ní nǹkankan, kò gbọdọ̀ gba ọlọ tabi ọmọ ọlọ tí ẹni náà fi ń lọ ọkà gẹ́gẹ́ bíi ìdógò, nítorí pé bí ó bá gba èyíkéyìí ninu mejeeji, bí ìgbà tí ó gba ẹ̀mí eniyan ni. “Bí ẹnìkan bá jí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Israẹli ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ gbé, tí ó sì ń lò ó gẹ́gẹ́ bí ẹrú, tabi tí ó tà á, pípa ni ẹ gbọdọ̀ pa olúwarẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú ohun burúkú yìí kúrò láàrin yín. “Bí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá mú yín, ẹ ṣọ́ra gidigidi, kí ẹ sì rí i pé ẹ ṣe gbogbo ohun tí àwọn alufaa, ọmọ Lefi, bá là sílẹ̀ fun yín láti ṣe, gẹ́gẹ́ bí mo ti pàṣẹ fún wọn. Ẹ ranti ohun tí OLUWA Ọlọrun yín ṣe sí Miriamu nígbà tí ẹ̀ ń jáde ti ilẹ̀ Ijipti bọ̀. “Tí ẹ bá yá ẹnìkejì yín ní nǹkankan, ẹ kò gbọdọ̀ wọ ilé rẹ̀ lọ láti wá ohun tí yóo fi dógò. Ìta ni kí ẹ dúró sí, kí ẹ sì jẹ́ kí ó fi ọwọ́ ara rẹ̀ mú un wá fun yín. Bí ó bá jẹ́ aláìní ni olúwarẹ̀, aṣọ tí ó bá fi dógò kò gbọdọ̀ sùn lọ́dọ̀ yín. Ẹ gbọdọ̀ dá a pada fún un ní alẹ́, kí ó lè rí aṣọ fi bora sùn, kí ó lè súre fun yín. Èyí yóo jẹ́ ìwà òdodo lójú OLUWA Ọlọrun yín. “Ẹ kò gbọdọ̀ rẹ́ alágbàṣe yín tí ó jẹ́ talaka ati aláìní jẹ, kì báà jẹ́ ọmọ Israẹli ẹlẹgbẹ́ yín, tabi àlejò tí ó ń gbé ọ̀kan ninu àwọn ìlú yín. Lojoojumọ, kí oòrùn tó wọ̀, ni kí ẹ máa san owó iṣẹ́ òòjọ́ rẹ̀ fún un, nítorí pé ó nílò owó yìí, kò sì sí ohun mìíràn tí ó gbẹ́kẹ̀lé. Bí ẹ kò bá san án fún un, yóo ké pe OLUWA, yóo sì di ẹ̀ṣẹ̀ sí yín lọ́rùn. “Ẹ kò gbọdọ̀ pa baba dípò ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ kò gbọdọ̀ pa ọmọ dípò baba, olukuluku ni yóo kú fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó bá dá. “Ẹ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ òdodo tí ó tọ́ sí àlejò tabi aláìníbaba po, bẹ́ẹ̀ sì ni, tí ẹ bá yá opó ní ohunkohun, ẹ kò gbọdọ̀ gba aṣọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò. Ṣugbọn ẹ ranti pé ẹ̀yin náà ti jẹ́ ẹrú rí ní ilẹ̀ Ijipti, ati pé OLUWA Ọlọrun yín ni ó rà yín pada níbẹ̀, nítorí náà ni mo fi ń pàṣẹ fun yín láti ṣe èyí. “Nígbà tí ẹ bá ń kórè ọkà ninu oko yín, tí ẹ bá gbàgbé ìdì ọkà kan sinu oko, ẹ kò gbọdọ̀ pada lọ gbé e. Ẹ fi sílẹ̀ fún àwọn àlejò ati àwọn aláìní baba ati àwọn opó, kí OLUWA Ọlọrun yín lè bukun iṣẹ́ ọwọ́ yín. Bí ẹ bá ti ká èso olifi yín, ẹ kò gbọdọ̀ pada sẹ́yìn láti ká àwọn èso tí ẹ bá gbàgbé. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn àlejò ati àwọn aláìní baba ati àwọn opó. Bí ẹ bá ti ká èso àjàrà yín, ẹ kò gbọdọ̀ pada sẹ́yìn láti ká àwọn èso tí ẹ bá gbàgbé. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn àlejò ati àwọn opó ati àwọn aláìní baba. Ẹ ranti pé ẹ ti jẹ́ ẹrú rí ní ilẹ̀ Ijipti, nítorí náà ni mo fi pàṣẹ fun yín láti ṣe èyí. “Bí èdè-àìyedè kan bá bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ meji, tí wọ́n bá lọ sí ilé ẹjọ́, tí àwọn adájọ́ sì dá ẹjọ́ náà fún wọn, tí wọ́n dá ẹni tí ó jàre láre, tí wọ́n sì dá ẹni tí ó jẹ̀bi lẹ́bi, bí ó bá jẹ́ pé nínà ni ó yẹ kí wọ́n na ẹni tí ó jẹ̀bi, ẹni náà yóo dọ̀bálẹ̀ níwájú adájọ́, wọn yóo sì nà án ní iye ẹgba tí ó bá tọ́ sí i gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ṣugbọn wọn kò gbọdọ̀ nà án ju ogoji ẹgba lọ, ohun ìtìjú ni yóo jẹ́ fún un ní gbangba, bí wọ́n bá nà án jù bẹ́ẹ̀ lọ. “Ẹ kò gbọdọ̀ dí mààlúù lẹ́nu nígbà tí ẹ bá ń lò ó láti fi pa ọkà. “Bí àwọn arakunrin meji bá jùmọ̀ ń gbé pọ̀, tí ọ̀kan ninu wọn sì kú láìní ọmọkunrin, aya ẹni tí ó kú kò gbọdọ̀ lọ fẹ́ ará ìta tabi àlejò. Arakunrin ọkọ rẹ̀ ni ó gbọdọ̀ ṣú u lópó, kí ó sì máa ṣe gbogbo ẹ̀tọ́ tí ó bá yẹ fún obinrin náà. Wọn yóo ka ọmọkunrin kinni tí opó yìí bá bí sí ọmọ ọkọ rẹ̀ tí ó kú, kí orúkọ ọkọ rẹ̀ náà má baà parẹ́ ní Israẹli. Bí ọkunrin yìí kò bá wá fẹ́ ṣú aya arakunrin rẹ̀ tí ó kú lópó, obinrin náà yóo tọ àwọn àgbààgbà lọ ní ẹnubodè, yóo sì wí pé, ‘Arakunrin ọkọ mi kọ̀ láti gbé orúkọ arakunrin rẹ̀ ró ní Israẹli, ó kọ̀ láti ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí arakunrin ọkọ mi.’ Àwọn àgbààgbà ìlú yóo pe ọkunrin náà, wọn óo bá a sọ̀rọ̀, bí ó bá kọ̀ jálẹ̀, tí ó wí pé, ‘Èmi kò fẹ́ fẹ́ ẹ,’ Lẹ́yìn náà, obinrin náà yóo tọ̀ ọ́ lọ lójú gbogbo àwọn àgbààgbà, yóo bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀, yóo tutọ́ sí i lójú, yóo sì wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe sí ẹni tí ó bá kọ̀ láti kọ́ ilé arakunrin rẹ̀.’ Wọn yóo sì máa pe ìdílé rẹ̀ ní ìdílé ẹni tí wọ́n bọ́ bàtà lẹ́sẹ̀ rẹ̀. “Bí ọkunrin meji bá ń jà, tí iyawo ọ̀kan ninu wọn bá sáré wá láti gbèjà ọkọ rẹ̀ tí wọn ń lù, tí ó bá fa nǹkan ọkunrin ẹni tí ń lu ọkọ rẹ̀ yìí, gígé ni kí ẹ gé ọwọ́ rẹ̀, ẹ kò gbọdọ̀ ṣàánú rẹ̀ rárá. “O kò gbọdọ̀ ní oríṣìí ìwọ̀n meji ninu àpò rẹ, kí ọ̀kan kéré, kí ekeji sì tóbi. O kò gbọdọ̀ ní oríṣìí òṣùnwọ̀n meji ninu ilé rẹ, kí ọ̀kan kéré, kí ekeji sì tóbi. Ṣugbọn ìwọ̀n ati òṣùnwọ̀n rẹ gbọdọ̀ péye, kí ọjọ́ rẹ lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun rẹ fún ọ. Nítorí pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe aiṣootọ, ìríra ni lójú OLUWA Ọlọrun yín. “Ẹ ranti ohun tí àwọn ará Amaleki ṣe sí yín nígbà tí ẹ̀ ń bọ̀ láti Ijipti. Wọn kò bẹ̀rù Ọlọrun, ṣugbọn wọ́n gbógun tì yín lójú ọ̀nà nígbà tí ó ti rẹ̀ yín, wọ́n sì pa gbogbo àwọn tí wọn ń bọ̀ lẹ́yìn. Nítorí náà nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá fun yín ní ìṣẹ́gun lórí gbogbo àwọn ọ̀tá yín tí wọ́n wà ní àyíká yín, ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, pípa ni kí ẹ pa àwọn ará Amaleki run lórí ilẹ̀ ayé. Ẹ kò gbọdọ̀ gbàgbé. “Nígbà tí o bá dé orí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun rẹ fún ọ, tí o gbà á, tí o sì ń gbé inú rẹ̀, mú ninu àkọ́so èso ilẹ̀ náà sinu agbọ̀n kan, kí o sì gbé e lọ sí ibi tí OLUWA Ọlọrun rẹ yóo yàn pé kí ẹ ti máa sin òun. Tọ alufaa tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ní àkókò náà lọ, kí o sì wí fún un pé, ‘Mò ń wí fún OLUWA Ọlọrun mi lónìí pé, mo ti dé ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba wa láti fún wa.’ “Alufaa yóo gba agbọ̀n èso náà ní ọwọ́ rẹ, yóo sì gbé e kalẹ̀ níwájú pẹpẹ OLUWA Ọlọrun rẹ. Lẹ́yìn náà, o óo wí báyìí níwájú OLUWA Ọlọrun rẹ pé, ‘Ará Aramea, alárìnká, ni baba ńlá mi, ó lọ sí ilẹ̀ Ijipti, ó sì jẹ́ àlejò níbẹ̀. Wọn kò pọ̀ rárá tẹ́lẹ̀, ṣugbọn níbẹ̀ ni wọ́n ti di pupọ, wọ́n sì di orílẹ̀-èdè ńlá, tí ó lágbára, tí ó sì lókìkí. Àwọn ará Ijipti lò wá ní ìlò ìkà, wọ́n pọ́n wa lójú, wọ́n sì mú wa sìn bí ẹrú. A bá kígbe pe OLUWA Ọlọrun àwọn baba wa; ó gbọ́ ohùn wa, ó rí ìpọ́njú, ati ìṣẹ́, ati ìjìyà wa. OLUWA fi agbára rẹ̀ kó wa jáde láti Ijipti, pẹlu àwọn iṣẹ́ àmì ati iṣẹ́ ìyanu. Ó kó wa wá sí ìhín, ó sì fún wa ní ilẹ̀ yìí; ilẹ̀ tí ó ní ọ̀rá tí ó kún fún wàrà ati oyin. Nítorí náà, nisinsinyii, mo mú àkọ́so èso ilẹ̀ tí ìwọ OLUWA ti fi fún mi wá.’ “Lẹ́yìn náà, gbé e kalẹ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun rẹ, kí o sì sìn ín; kí o sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ fún ohun tí OLUWA fún ìwọ ati ìdílé rẹ, kí àwọn ọmọ Lefi ati àwọn àlejò tí ń gbé ààrin yín náà sì máa bá ọ ṣe àjọyọ̀. “Ní ọdún kẹtakẹta, tíí ṣe ọdún ìdámẹ́wàá, tí o bá ti dá ìdámẹ́wàá gbogbo ìkórè oko rẹ, kí o kó wọn fún àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn àlejò, ati àwọn aláìní baba, ati àwọn opó, kí wọ́n lè máa jẹ àjẹyó ninu ìlú yín. Lẹ́yìn náà, kí o wí níwájú OLUWA Ọlọrun rẹ pé, ‘Gbogbo ìdámẹ́wàá tíí ṣe ohun ìyàsímímọ́ ni mo ti mú kúrò ninu ilé mi, mo sì ti fi fún àwọn ọmọ Lefi ati àwọn àlejò, ati àwọn aláìní baba, ati àwọn opó, gẹ́gẹ́ bíi gbogbo àṣẹ tí o pa fún mi. N kò rú èyíkéyìí ninu àwọn òfin rẹ, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì gbàgbé wọn. N kò jẹ ninu ìdámẹ́wàá mi nígbà tí mò ń ṣọ̀fọ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò kó èyíkéyìí jáde kúrò ninu ilé mi nígbà tí mo jẹ́ aláìmọ́, tabi kí n fi èyíkéyìí ninu wọn bọ òkú ọ̀run. Gbogbo ohun tí o wí ni mo ti ṣe, OLUWA Ọlọrun mi, mo sì ti pa gbogbo àṣẹ rẹ mọ́. Bojúwo ilẹ̀ láti ibùgbé mímọ́ rẹ lọ́run, kí o sì bukun Israẹli, àwọn eniyan rẹ, ati ilẹ̀ tí o ti fi fún wa gẹ́gẹ́ bí o ti ṣèlérí fún àwọn baba wa, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin.’ “OLUWA Ọlọrun rẹ pàṣẹ fún ọ lónìí, pé kí o máa pa gbogbo ìlànà ati òfin wọnyi mọ́. Nítorí náà, máa pa gbogbo wọn mọ́ tọkàntọkàn. O ti fi ẹnu ara rẹ sọ lónìí pé, OLUWA ni Ọlọrun rẹ, ati pé o óo máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀, o óo máa pa gbogbo ìlànà ati òfin ati ìdájọ́ rẹ̀ mọ́, o óo sì máa gbọ́ tirẹ̀. OLUWA pàápàá sì ti sọ lónìí pé, eniyan òun ni ọ́, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún ọ, ati pé kí o pa gbogbo òfin òun mọ́. Ó ní òun óo gbé ọ ga ju gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí ó dá lọ. O óo níyì jù wọ́n lọ; o óo ní òkìkí jù wọ́n lọ, o óo sì lọ́lá jù wọ́n lọ. O óo jẹ́ ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún OLUWA Ọlọrun rẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí.” Mose, pẹlu gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli, sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ máa pa gbogbo òfin tí mo fun yín lónìí mọ́. Ní ọjọ́ tí ẹ bá kọjá odò Jọdani, tí ẹ bá ti wọ inú ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fun yín, ẹ to òkúta ńláńlá jọ kí ẹ fi ohun tí wọ́n fi ń rẹ́ ilé rẹ́ ẹ. Ẹ kọ gbogbo òfin wọnyi sára rẹ̀, nígbà tí ẹ bá ń rékọjá lọ láti wọ ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fun yín, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín ti ṣèlérí fun yín. Nígbà tí ẹ bá rékọjá sí òdìkejì odò Jọdani, ẹ to àwọn òkúta tí mo paláṣẹ fun yín lónìí jọ lórí òkè Ebali, kí ẹ sì fi ohun tí wọ́n fi ń rẹ́ ilé rẹ́ ẹ. Ẹ fi òkúta kọ́ pẹpẹ kan fún OLUWA níbẹ̀; ẹ kò gbọdọ̀ fi irin gbẹ́ òkúta náà rárá. Òkúta tí wọn kò gbẹ́ ni kí ẹ fi kọ́ pẹpẹ kan fún OLUWA Ọlọrun yín kí ẹ sì rú ẹbọ sísun sí i lórí rẹ̀. Ẹ rú ẹbọ alaafia, kí ẹ jẹ ẹ́ níbẹ̀, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín. Ẹ kọ gbogbo àwọn òfin wọnyi sára òkúta náà, ẹ kọ wọ́n kí wọ́n hàn ketekete.” Mose ati àwọn alufaa, ọmọ Lefi, bá wí fún gbogbo ọmọ Israẹli pé, “Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́, kí ẹ sì gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, òní ni ẹ di eniyan OLUWA Ọlọrun yín. Nítorí náà ẹ gbọdọ̀ máa gbọ́ràn sí OLUWA Ọlọrun yín lẹ́nu, kí ẹ sì máa pa òfin ati ìdájọ́ rẹ̀ mọ́, bí èmi Mose ti pàṣẹ fun yín lónìí.” Mose bá pàṣẹ fún àwọn eniyan náà ní ọjọ́ kan náà, ó ní, “Nígbà tí ẹ bá kọjá odò Jọdani sí òdìkejì, àwọn ẹ̀yà Simeoni, ẹ̀yà Lefi, ti Juda, ti Isakari, ti Josẹfu ati ti Bẹnjamini yóo dúró lórí òkè Gerisimu láti súre. Àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi, ti Aṣeri, ti Sebuluni, ti Dani ati ti Nafutali yóo sì dúró lórí òkè Ebali láti búra. Àwọn ọmọ Lefi yóo wí ketekete fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pé: “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá yá ère gbígbẹ́ tabi ère tí wọ́n fi irin rọ. Ohun ìríra ni lójú OLUWA, pé kí àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà fi ọwọ́ gbẹ́ nǹkan, kí ẹnìkan wá gbé e kalẹ̀ níkọ̀kọ̀, kí ó máa bọ ọ́.’ “Gbogbo àwọn eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’ “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá tàbùkù baba tabi ìyá rẹ̀.’ “Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’ “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá yẹ ààlà ilẹ̀ ẹnìkejì rẹ̀.’ “Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’ “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣi afọ́jú lọ́nà.’ “Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’ “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹni tí ó bá yí ìdájọ́ òdodo tí ó tọ́ sí àlejò po, tabi ti aláìní baba, tabi ti opó.’ “Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’ “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá bá aya baba rẹ̀ lòpọ̀, nítorí pé ó dójúti baba rẹ̀.’ “Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’ “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹranko lòpọ̀.’ “Gbogbo eniyan yóo dáhùn pé, ‘Amin.’ “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá bá arabinrin rẹ̀ lòpọ̀, kì báà jẹ́ ọmọ ìyá rẹ̀ tabi ọmọ baba rẹ̀.’ “Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’ “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ìyá aya rẹ̀ lòpọ̀.’ “Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’ “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá pa aládùúgbò rẹ̀ níkọ̀kọ̀.’ “Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’ “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti pa aláìṣẹ̀.’ “Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’ “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí kò bá pa gbogbo àwọn òfin yìí mọ́, kí ó sì máa tẹ̀lé wọn.’ “Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’ “Bí o bá gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun rẹ, tí o sì farabalẹ̀ pa gbogbo òfin rẹ̀, tí mo ṣe fún ọ lónìí mọ́, OLUWA Ọlọrun rẹ yóo gbé ọ ga ju gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù láyé lọ. Gbogbo ibukun wọnyi ni yóo mọ́ ọ lórí, tí yóo sì ṣẹ sí ọ lára, bí o bá gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun rẹ. “OLUWA yóo bukun ọ ní ààrin ìlú, yóo sì bukun oko rẹ. “Yóo bukun àwọn ọmọ rẹ, ati èso ilẹ̀ rẹ, ati àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ, ati àwọn ọmọ mààlúù rẹ, ati àwọn ọmọ aguntan rẹ. “OLUWA yóo fi ibukun rẹ̀ sí orí ọkà rẹ, ati oúnjẹ rẹ. “Yóo bukun ọ nígbà tí o bá ń wọlé, yóo sì tún bukun ọ nígbà tí o bá ń jáde. “Yóo bá ọ ṣẹgun àwọn ọ̀tá tí ó bá dìde sí ọ. Bí wọ́n bá gba ọ̀nà kan dìde sí ọ, yẹ́lẹyẹ̀lẹ ni wọn óo fọ́nká nígbà tí wọn bá ń sálọ fún ọ. “OLUWA yóo bukun ìkórè inú àká rẹ, ati gbogbo nǹkan tí o bá dáwọ́ lé. OLUWA Ọlọrun rẹ yóo bukun ọ ní ilẹ̀ tí ó fún ọ. “OLUWA yóo ṣe ọ́ ní eniyan rẹ̀, tí ó yà sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún ọ, bí o bá pa òfin rẹ̀ mọ́, tí o sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀. Gbogbo eniyan ayé ni yóo rí i pé orúkọ OLUWA ni wọ́n fi ń pè ọ́, wọn yóo sì máa bẹ̀rù rẹ. OLUWA óo fún ọ ní ọpọlọpọ ọmọ, ati ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn. Àwọn igi eléso rẹ yóo máa so jìnwìnnì ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun rẹ búra fún àwọn baba rẹ, pé òun yóo fún ọ. OLUWA yóo fún ọ ní ọpọlọpọ òjò ní àkókò rẹ̀ láti inú ilé ìṣúra rẹ̀ lójú ọ̀run, yóo sì bukun iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Ìwọ ni o óo máa yá ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ní nǹkan, o kò sì ní tọrọ lọ́wọ́ wọn. OLUWA yóo fi ọ́ ṣe orí, o kò ní di ìrù; òkè ni o óo máa lọ, o kò ní di ẹni ilẹ̀; bí o bá pa òfin OLUWA Ọlọrun rẹ, tí mo pa láṣẹ fún ọ lónìí mọ́, tí o mú gbogbo wọn ṣẹ lẹ́sẹẹsẹ, tí o kò bá yipada ninu àwọn òfin tí mo ṣe fún ọ lónìí, tí o kò sì sá tọ àwọn oriṣa lọ, láti máa bọ wọ́n. “Ṣugbọn bí o kò bá gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun rẹ, tí o kò sì pa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀ mọ́, bí mo ti fi lélẹ̀ fún ọ lónìí, gbogbo àwọn ègún wọnyi ni yóo ṣẹ sí orí rẹ tí yóo sì mọ́ ọ. “Ègún ni fún ọ ní ààrin ìlú, ègún ni fún ọ ní oko. “Ègún ni fún ọkà rẹ ati oúnjẹ rẹ. “Ègún ni fún ọmọ inú rẹ, ati fún èso ilẹ̀ rẹ ati fún àwọn ọmọ mààlúù rẹ ati àwọn ọmọ aguntan rẹ. “Ègún ni fún ọ nígbà tí o bá wọlé, ègún sì ni fún ọ nígbà tí o bá jáde. “Bí o bá ṣe ibi, tí o kọ OLUWA sílẹ̀, ninu gbogbo nǹkan tí o bá dáwọ́ lé, èmi OLUWA yóo da ègún lé ọ lórí, n óo sì mú ìdàrúdàpọ̀ ati wahala bá ọ, títí tí o óo fi parun patapata, láìpẹ́, láìjìnnà. OLUWA yóo rán àjàkálẹ̀ àrùn sí ọ títí tí yóo fi pa ọ́ run patapata, lórí ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti gbà. OLUWA yóo fi àrùn jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ ṣe ọ́, ati ibà, ìgbóná ati ooru; yóo sì rán ọ̀gbẹlẹ̀, ọ̀dá, ati ìrẹ̀dànù sí ohun ọ̀gbìn rẹ, títí tí o óo fi parun. Òjò kò ní rọ̀, ilẹ̀ yóo sì le bí àpáta. Dípò òjò, eruku ni yóo máa dà bò ọ́ láti ojú ọ̀run, títí tí o óo fi parun patapata. “OLUWA yóo jẹ́ kí àwọn ọ̀tá rẹ ṣẹgun rẹ. Bí o bá jáde sí wọn ní ọ̀nà kan, OLUWA yóo tú ọ ká níwájú wọn. Ọ̀rọ̀ rẹ yóo sì di ìyanu ati ẹ̀rù ní gbogbo orílẹ̀-èdè ayé. Òkú rẹ yóo di ìjẹ fún àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko tí ń káàkiri orí ilẹ̀ ayé, kò sì ní sí ẹnikẹ́ni tí óo lé wọn kúrò. OLUWA yóo da irú oówo tí ó fi bá àwọn ará Ijipti jà bò ọ́, ati egbò, èkúkú ati ẹ̀yi, tí ẹnikẹ́ni kò ní lè wòsàn. OLUWA yóo da wèrè, ìfọ́jú, ati ìdàrúdàpọ̀ ọkàn bò ọ́. O óo máa táràrà lọ́sàn-án gangan bí afọ́jú. Kò ní dára fún ọ ní gbogbo ọ̀nà rẹ. Wọn yóo máa ni ọ́ lára, wọn yóo sì máa jà ọ́ lólè nígbà gbogbo; kò sì ní sí ẹnìkan láti ràn ọ́ lọ́wọ́. “O óo fẹ́ iyawo sọ́nà, ẹlòmíràn ni yóo máa bá a lòpọ̀. O óo kọ́ ilé, o kò sì ní gbé inú rẹ̀. O óo gbin ọgbà àjàrà, o kò sì ní jẹ ninu èso rẹ̀. Wọn óo máa pa akọ mààlúù rẹ lójú rẹ, o kò ní fẹnu kàn ninu rẹ̀. Wọn óo fi tipátipá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ lọ lójú rẹ, wọn kò sì ní dá a pada fún ọ mọ́. Àwọn aguntan yín yóo di ti àwọn ọ̀tá yín, kò sì ní sí ẹni tí yóo ràn yín lọ́wọ́. Àwọn ọmọ yín ọkunrin ati àwọn ọmọ yín obinrin óo di ti ẹni ẹlẹ́ni. Ẹ óo retí wọn títí, ẹ kò ní gbúròó wọn, kò sì ní sí ohunkohun tí ẹ lè ṣe sí i. Orílẹ̀-èdè tí ẹ kò mọ̀ rí ni yóo jẹ ohun ọ̀gbìn yín ati gbogbo làálàá yín ní àjẹrun. Ìnilára ati ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ni ẹ óo máa rí nígbà gbogbo, tóbẹ́ẹ̀ tí ohun tí ẹ óo máa fi ojú yín rí yóo yà yín ní wèrè. OLUWA yóo da oówo burúkú bò yín lẹ́sẹ̀ ati lórúnkún, yóo burú tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ní lè wò yín sàn. Láti àtẹ́lẹsẹ̀ yín títí dé àtàrí yín kìkì oówo ni yóo jẹ́. “OLUWA yóo lé ẹ̀yin ati ẹni tí ẹ bá fi jọba yín lọ sí orílẹ̀-èdè tí ẹ̀yin ati àwọn baba yín kò mọ̀ rí, ẹ óo sì máa bọ oríṣìíríṣìí oriṣa tí wọ́n fi igi ati òkúta gbẹ́ níbẹ̀. Ẹ óo di ẹni ìríra, ẹni àmúpòwe ati ẹni ẹ̀sín, láàrin gbogbo àwọn eniyan, níbi tí OLUWA yóo le yín lọ. “Ọpọlọpọ èso ni ẹ óo máa gbìn sinu oko yín, ṣugbọn díẹ̀ ni ẹ óo máa rí ká, nítorí eṣú ni yóo máa jẹ wọ́n. Ẹ óo gbin ọgbà àjàrà, ẹ óo sì tọ́jú rẹ̀, ṣugbọn ẹ kò ní rí èso rẹ̀ ká, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní mu ninu ọtí rẹ̀, nítorí pé àwọn kòkòrò yóo ti jẹ ẹ́. Gbogbo ilẹ̀ yín yóo kún fún igi olifi, ṣugbọn ẹ kò ní rí òróró fi pa ara, nítorí pé rírẹ̀ ni èso olifi yín yóo máa rẹ̀ dànù. Ẹ óo bí ọpọlọpọ ọmọkunrin ati ọmọbinrin, ṣugbọn wọn kò ní jẹ́ tiyín, nítorí gbogbo wọn ni wọn óo kó lẹ́rú lọ. Gbogbo igi yín ati gbogbo èso ilẹ̀ yín ni yóo di ti àwọn eṣú. “Àwọn àlejò tí wọ́n wà láàrin yín yóo máa níláárí jù yín lọ, ọwọ́ wọn yóo máa ròkè, ṣugbọn ní tiyín, ẹ óo di ẹni ilẹ̀ patapata. Ọwọ́ àlejò yín ni ẹ óo ti máa tọrọ nǹkan, àwọn kò sì ní tọrọ ohunkohun lọ́wọ́ yín. Àwọn ni wọn yóo jẹ́ orí fun yín, ẹ̀yin yóo sì jẹ́ ìrù fún wọn. “Gbogbo ègún wọnyi ni yóo ṣẹ si yín lára, tí yóo sì lẹ̀ mọ́ yín pẹ́kípẹ́kí títí tí ẹ óo fi parun, nítorí pé ẹ kò gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín, ẹ kò pa òfin rẹ̀ mọ́, ẹ kò sì tẹ̀lé àwọn ìlànà tí ó pa láṣẹ fun yín. Àwọn ègún náà yóo wà lórí yín gẹ́gẹ́ bí àmì ati ohun ìyanu, ati lórí àwọn arọmọdọmọ yín títí lae. Nítorí pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọrun bukun yín, ẹ kọ̀, ẹ kò sìn ín pẹlu ayọ̀ ati inú dídùn. Nítorí náà, ní ìhòòhò, pẹlu ebi ati òùngbẹ, ati àìní ni ẹ óo fi máa sin àwọn ọ̀tá tí OLUWA yóo rán si yín, yóo sì la àjàgà irin bọ̀ yín lọ́rùn títí tí yóo fi pa yín run. OLUWA yóo gbé orílẹ̀-èdè kan, tí ẹ kò gbọ́ èdè wọn, dìde si yín láti òpin ayé; wọn óo yára bí àṣá. Ojú gbogbo wọn óo pọ́n kankan, wọn kò ní ṣàánú ọmọde, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní bọ̀wọ̀ fún àgbà. Wọn yóo jẹ àwọn ọmọ ẹran yín ati èso ilẹ̀ yín títí tí ẹ óo fi parun patapata. Wọn kò ní ṣẹ́ nǹkankan kù fun yín ninu ọkà yín, ọtí waini yín, ati òróró yín, àwọn ọmọ mààlúù tabi ọmọ aguntan yín; títí tí wọn yóo fi jẹ yín run. Gbogbo ìlú ńláńlá yín ni wọn óo dó tì, títí tí gbogbo odi gíga tí ẹ gbójúlé, tí ó yí àwọn ìlú ńláńlá yín po, yóo fi wó lulẹ̀, ní gbogbo ilẹ̀ yín. Gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní gbogbo ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín ni wọn yóo dó tì. “Ojú yóo pọn yín tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, nígbà tí àwọn ọ̀tá yin bá dó tì yín, tí yóo fi jẹ́ pé àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin, tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, ni ẹ óo máa pa jẹ. Ọkunrin tí àwọ̀ rẹ̀ tutù jùlọ, tí ó sì jẹ́ afínjú jùlọ ninu àwọn ọkunrin yín, yóo di ahun sí arakunrin rẹ̀, ati sí iyawo rẹ̀ tí ó fẹ́ràn jùlọ, ati sí ọmọ rẹ̀ tí ó kù ú kù, tóbẹ́ẹ̀ tí kò ní fún ẹnikẹ́ni jẹ ninu ẹran ara ọmọ rẹ̀ tí ó bá ń jẹ ẹ́; nítorí pé kò sí nǹkankan tí ó kù fún un mọ́, ninu ìnira tí àwọn ọ̀tá yín yóo kó yín sí nígbà tí wọ́n ba dó ti àwọn ìlú yín. Obinrin tí àwọ̀ rẹ̀ tutù jùlọ, tí ó sì jẹ́ afínjú jùlọ ninu àwọn obinrin yín, tí kò jẹ́ fi ẹsẹ̀ lásán tẹ ilẹ̀ nítorí àwọ̀ rẹ̀ tí ó tutù ati ìwà afínjú rẹ̀, yóo di ahun sí ọkọ tí ó jẹ́ olùfẹ́ rẹ̀, ati ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin. Yóo bímọ tán, yóo sì jẹ ibi ọmọ tí ó jáde lára rẹ̀ ní kọ̀rọ̀, yóo sì tún jẹ ọmọ titun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, nítorí pé kò sí ohun tí ó lè jẹ mọ́, nítorí àwọn ọ̀tá yín tí yóo dó ti àwọn ìlú yín. “Bí ẹ bá kọ̀, tí ẹ kò tẹ̀lé gbogbo òfin tí a kọ sinu ìwé yìí, pé kí ẹ máa bẹ̀rù orúkọ OLUWA Ọlọrun yín, tí ó lẹ́rù, tí ó sì lógo, OLUWA yóo mú ìpọ́njú ńlá bá ẹ̀yin ati arọmọdọmọ yín, ìpọ́njú ńlá ati àìsàn burúkú, tí yóo wà lára yín fún ìgbà pípẹ́. Gbogbo àwọn àrùn burúkú ilẹ̀ Ijipti, tí wọ́n bà yín lẹ́rù, ni OLUWA yóo dà bò yín, tí yóo sì wà lára yín. Àwọn àìsàn mìíràn ati ìpọ́njú tí wọn kò kọ sinu ìwé òfin yìí ni OLUWA yóo dà bò yín títí tí ẹ óo fi parun. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ẹ kò ni kù ju díẹ̀ lọ mọ́, nítorí pé ẹ kò gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín. Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ dídùn inú OLUWA láti ṣe yín ní rere ati láti sọ yín di pupọ, bákan náà ni yóo jẹ́ dídùn inú rẹ̀ láti ba yín kanlẹ̀ kí ó sì pa yín run. OLUWA yóo le yín kúrò lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ láti gbà. OLUWA yóo fọ́n yín káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè ayé, ẹ óo sì máa bọ oríṣìíríṣìí oriṣa káàkiri, ati èyí tí wọ́n fi igi gbẹ́, ati èyí tí wọn fi òkúta ṣe, tí ẹ̀yin ati àwọn baba yín kò mọ̀ rí. Ara kò ní rọ̀ yín rárá láàrin àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní rí ìdí jókòó. OLUWA yóo mú jìnnìjìnnì ati ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn ba yín, yóo sì mú kí ojú yín di bàìbàì. Ninu hílàhílo ni ẹ óo máa wà nígbà gbogbo, ninu ẹ̀rù ati ìpayà ni ẹ óo máa wà tọ̀sán-tòru. Àwọn ohun tí ojú yín yóo máa rí yóo kó ìpayà ati ẹ̀rù ba yín, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo fi jẹ́ pé, bí ilẹ̀ bá ti ṣú, yóo dàbí kí ilẹ̀ ti mọ́; bí ilẹ̀ bá sì ti tún mọ́, yóo dàbí kí ilẹ̀ ti ṣú. Ọkọ̀ ojú omi ni OLUWA yóo fi ko yín pada sí ilẹ̀ Ijipti, níbi tí mo ti ṣèlérí pé ẹ kò ní pada sí mọ́ lae. Nígbà tí ẹ bá débẹ̀, ẹ óo fa ara yín kalẹ̀ fún títà gẹ́gẹ́ bí ẹrú, lọkunrin ati lobinrin, ṣugbọn ẹ kò ní rí ẹni rà yín.” OLUWA pàṣẹ fún Mose pé kí ó bá àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu mìíràn ní ilẹ̀ Moabu, yàtọ̀ sí èyí tí ó ti bá wọn dá ní òkè Horebu. Mose pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ ti rí gbogbo ohun tí OLUWA ṣe sí Farao ati àwọn iranṣẹ rẹ̀, ati gbogbo ilẹ̀ rẹ̀, ní ilẹ̀ Ijipti. Ẹ fi ojú yín rí àwọn ìdààmú ńláńlá tí ó bá wọn, ati àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá tí OLUWA ṣe. Ṣugbọn títí di òní yìí, OLUWA kò tíì jẹ́ kí òye ye yín, ojú yín kò ríran, bẹ́ẹ̀ ni etí yín kò gbọ́ràn. Odidi ogoji ọdún ni mo fi ko yín la ààrin aṣálẹ̀ kọjá. Aṣọ kò gbó mọ yín lára, bẹ́ẹ̀ ni bàtà kò gbó mọ yín lẹ́sẹ̀. Ẹ kò jẹ oúnjẹ gidi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mu ọtí waini tabi ọtí líle, kí ẹ lè mọ̀ pé OLUWA ni OLUWA Ọlọrun yín. Nígbà tí ẹ dé ibí yìí, Sihoni, ọba Heṣiboni ati Ogu, ọba Baṣani gbógun tì wá, ṣugbọn a ṣẹgun wọn. A gba ilẹ̀ wọn, a sì fi fún ẹ̀yà Reubẹni, ati ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase, gẹ́gẹ́ bí ìpín tiwọn. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra yín, kí ẹ máa tẹ̀lé majẹmu yìí, kí ohun gbogbo tí ẹ bá dáwọ́lé lè máa yọrí sí rere. “Gbogbo yín pátá ni ẹ dúró níwájú OLUWA Ọlọrun yín lónìí, ati gbogbo àwọn olórí ninu àwọn ẹ̀yà yín, ati àwọn àgbààgbà ati àwọn olóyè ati àwọn ọkunrin Israẹli. Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ yín, àwọn aya yín, ati àwọn àlejò tí wọn ń gbé orí ilẹ̀ yín; àwọn tí wọn ń wá igi fun yín, ati àwọn tí wọn ń pọnmi fun yín. Kí gbogbo yín lè bá OLUWA Ọlọrun yín dá majẹmu lónìí, kí ó lè fi ìdí yín múlẹ̀ bí eniyan rẹ̀, kí ó sì máa jẹ́ Ọlọrun yín; gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fun yín, ati bí ó ti búra fún Abrahamu, Isaaki, ati Jakọbu àwọn baba ńlá yín. ‘Kìí ṣe ẹ̀yin nìkan ni mò ń bá dá majẹmu yìí, tí mo sì ń búra fún, ṣugbọn ati àwọn tí wọn kò sí níhìn-ín lónìí, ati ẹ̀yin alára tí ẹ dúró níwájú OLUWA Ọlọrun yín lónìí, ni majẹmu náà wà fún.’ “Ẹ̀yin náà mọ̀ bí ayé wa ti rí ní ilẹ̀ Ijipti, ati bí a ti la ààrin àwọn orílẹ̀-èdè tí a gbà kọjá. Ẹ sì ti rí àwọn ohun ìríra wọn: àwọn oriṣa wọn tí wọ́n fi igi gbẹ́, èyí tí wọ́n fi òkúta gbẹ́, èyí tí wọ́n fi fadaka ṣe, ati èyí tí wọ́n fi wúrà ṣe. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra yín, kí á má ṣe rí ẹnikẹ́ni ninu yín, kì báà ṣe ọkunrin tabi obinrin, tabi ìdílé kan, tabi ẹ̀yà kan, tí ọkàn rẹ̀ yóo yipada kúrò lọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun yín lónìí, tí yóo sì lọ máa bọ àwọn oriṣa tí àwọn orílẹ̀-èdè náà ń bọ. Nítorí pé, irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóo dàbí igi tí ń so èso tí ó korò, tí ó sì ní májèlé ninu. Kí irú ẹni tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ majẹmu má baà dá ara rẹ̀ lọ́kàn le pé ‘Kò séwu, bí mo bá fẹ́ mo lè ṣe orí kunkun kí n sì máa tẹ̀lé ìmọ̀ ara mi.’ Èyí yóo kó ìparun bá gbogbo yín, ati àwọn tí wọn ń ṣe ibi ati àwọn tí wọn ń ṣe rere. OLUWA kò ní dáríjì olúwarẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, ibinu ńlá OLUWA ni yóo bá a. Gbogbo àwọn ègún tí a kọ sinu ìwé yìí yóo ṣẹ sí i lára, OLUWA yóo sì pa orúkọ olúwarẹ̀ rẹ́ kúrò láyé. OLUWA yóo dojú kọ òun nìkan, láti ṣe é ní ibi láàrin gbogbo ẹ̀yà Israẹli, gẹ́gẹ́ bí ègún tí ó wà ninu majẹmu, tí a kọ sinu ìwé òfin yìí. “Nígbà tí àwọn arọmọdọmọ yín tí wọn kò tíì bí, ati àwọn àlejò tí wọ́n bá wá láti ilẹ̀ òkèèrè bá rí ìpọ́njú, ati àrùn tí OLUWA yóo dà bo ilẹ̀ náà, tí wọ́n bá rí i tí gbogbo ilẹ̀ náà ti di imí ọjọ́ ati iyọ̀, tí gbogbo rẹ di eérú, tí koríko kankan kò lè hù lórí rẹ̀, bíi ìlú Sodomu ati Gomora, Adima ati Seboimu, tí OLUWA fi ibinu ńlá parẹ́, gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni yóo máa bèèrè pé, ‘Kí ló dé tí OLUWA fi sọ ilẹ̀ yìí dà báyìí? Kí ló dé tí ibinu ńlá OLUWA fi dé sórí ilẹ̀ yìí?’ Àwọn eniyan yóo sì máa dáhùn pé, ‘Nítorí pé wọn kò mú majẹmu OLUWA Ọlọrun ṣẹ, tí ó bá àwọn baba wọn dá nígbà tí ó kó wọn jáde ní ilẹ̀ Ijipti. Wọ́n ń bọ àwọn oriṣa tí wọn kò mọ̀ rí, tí OLUWA kò sì fi lé wọn lọ́wọ́. Ìdí nìyí tí inú fi bí OLUWA sí ilẹ̀ yìí, tí ó sì mú gbogbo ègún tí a kọ sinu ìwé yìí ṣẹ lé wọn lórí. OLUWA sì fi ibinu ńlá ati ìrúnú lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ wọn, ó sì fọ́n wọn dà sórí ilẹ̀ mìíràn gẹ́gẹ́ bí ó ti rí lónìí.’ “Àwọn nǹkan àṣírí mìíràn wà, tí kò hàn sí eniyan àfi OLUWA Ọlọrun wa nìkan, ṣugbọn àwọn nǹkan tí ó fihàn wá jẹ́ tiwa ati ti àwọn ọmọ wa títí lae, kí á lè máa ṣe àwọn nǹkan tí ó wà ninu ìwé òfin yìí. “Nígbà tí gbogbo àwọn ibukun tabi ègún tí mo gbé kalẹ̀ níwájú yín lónìí bá ṣẹ mọ́ yín lára, tí ẹ bá dé ààrin àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA yóo fọn yín ká sí, tí ẹ bá ranti anfaani tí ẹ ti sọnù, tí ẹ bá yipada sí OLUWA Ọlọrun yín, ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín; tí ẹ bá tún ń gbọ́ tirẹ̀, tí ẹ sì ń fi tọkàntọkàn tẹ̀lé gbogbo òfin tí mo ṣe fun yín lónìí, OLUWA Ọlọrun yín yóo dá ibukun yín pada, yóo ṣàánú yín, yóo sì tún ko yín pada láti ààrin àwọn orílẹ̀-èdè gbogbo tí ó fọn yín ká sí. Ibi yòówù tí OLUWA bá fọn yín ká sí ninu ayé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ òpin ayé, OLUWA yóo wa yín rí, yóo sì ko yín jọ. OLUWA Ọlọrun yín yóo tún da yín pada sí ilẹ̀ àwọn baba yín, ilẹ̀ náà yóo tún pada di tiyín, OLUWA yóo mú kí ó dára fun yín, yóo mú kí ẹ pọ̀ ju àwọn baba yín lọ. OLUWA Ọlọrun yín yóo fún ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín ní ẹ̀mí ìgbọràn tí ó fi jẹ́ pé ẹ óo fẹ́ràn rẹ̀ tọkàntọkàn, ẹ óo sì wà láàyè. OLUWA Ọlọrun yín yóo da àwọn ègún wọnyi sórí àwọn ọ̀tá yín tí wọ́n ṣe inúnibíni si yín. Ẹ óo tún máa gbọ́ ti OLUWA, ẹ óo sì máa pa àwọn òfin rẹ̀ tí mò ń fun yín lónìí mọ́. OLUWA Ọlọrun yín yóo bukun iṣẹ́ ọwọ́ yín lọpọlọpọ, ati àwọn ọmọ yín; àwọn ọmọ mààlúù yín, ati àwọn ohun ọ̀gbìn yín, nítorí inú OLUWA yóo tún dùn láti bukun yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe inú dídùn sí àwọn baba yín, bí ẹ bá gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ pa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀ mọ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin yìí, tí ẹ bá sì yipada tọkàntọkàn. “Nítorí pé òfin tí mo fun yín lónìí kò le jù fun yín, kì í sìí ṣe ohun tí apá yín kò ká. Kì í ṣe òkè ọ̀run ni ó wà, tí ẹ óo fi wí pé, ‘Ta ni yóo gun òkè ọ̀run lọ, tí yóo lọ bá wa mú un sọ̀kalẹ̀ wá, kí á lè gbọ́ kí á sì pa á mọ́?’ Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ní òdìkejì òkun tí ẹ óo fi wí pé, ‘Ta ni yóo la òkun kọjá fún wa, tí yóo lọ bá wa mú un wá kí á lè gbọ́ kí á sì pa á mọ́?’ Ṣugbọn nítòsí yín ni ọ̀rọ̀ náà wà, ó wà lẹ́nu yín, ó sì wà ninu ọkàn yín, tí ó fi jẹ́ pé ẹ lè ṣe é. “Wò ó, mo gbé ikú ati ìyè kalẹ̀ níwájú yín lónìí, bákan náà ni mo sì gbé ire ati ibi kalẹ̀. Tí ẹ bá pa òfin OLUWA Ọlọrun yín mọ́ bí mo ti fun yín lónìí, tí ẹ̀ fẹ́ràn rẹ̀, tí ẹ̀ ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀, tí ẹ sì ń pa àwọn òfin, ìlànà ati ìdájọ́ rẹ̀ mọ́, ẹ óo wà láàyè, ẹ óo sì máa pọ̀ sí i. OLUWA Ọlọrun yín yóo bukun yín ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà tí yóo sì di tiyín. Ṣugbọn bí ọkàn yín bá yipada, tí ẹ kọ̀, tí ẹ kò gbọ́ tirẹ̀, tí ẹ bá jẹ́ kí wọn fà yín lọ bọ àwọn oriṣa, tí ẹ sì ń sìn wọ́n, mo wí fun yín gbangba lónìí pé, ẹ óo parun. Ẹ kò ní pẹ́ rárá lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń gòkè Jọdani lọ gbà, tí yóo sì di tiyín. Mo fi ilẹ̀ ati ọ̀run ṣe ẹlẹ́rìí níwájú yín lónìí, pé mo fun yín ní anfaani láti yan ikú tabi ìyè, ati láti yan ibukun tabi ègún. Nítorí náà, ẹ yan ìyè kí ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín lè wà láàyè. Ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, ẹ máa gbọ́ tirẹ̀, kí ẹ sì máa súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí, kí ẹ lè wà láàyè, kí ẹ lè pẹ́ láyé, kí ẹ sì lè máa gbé orí ilẹ̀ tí OLUWA búra láti fún àwọn baba yín, àní Abrahamu, Isaaki, ati Jakọbu.” Mose tún bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀. Ó ní, “Òní ni mo di ẹni ọgọfa ọdún (120), kò ní ṣeéṣe fún mi mọ́, láti máa fò síhìn-ín sọ́hùn-ún. OLUWA ti wí fún mi pé, n kò ní gun òkè odò Jọdani yìí. OLUWA Ọlọrun yín tìkalára rẹ̀ ni yóo ṣiwaju yín lọ, yóo ba yín pa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè náà run, tí ẹ ó fi lè gba ilẹ̀ wọn. Joṣua ni yóo sì jẹ́ olórí, tí yóo máa ṣiwaju yín lọ, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti wí. Bí OLUWA ti ṣe sí Sihoni ati Ogu, ọba àwọn ará Amori, tí ó pa wọ́n run tàwọn ti ilẹ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ ni yóo ṣe sí àwọn orílẹ̀-èdè yìí. OLUWA yóo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́, ẹ óo sì ṣe wọ́n bí mo ti pa á láṣẹ fun yín ninu òfin tí mo fun yín. Ẹ múra gírí, kí ẹ sì mú ọkàn gidigidi. Ẹ má bẹ̀rù rárá, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí àyà fò yín; nítorí pé, OLUWA Ọlọrun yín ń ba yín lọ. Kò ní já yín kulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní fi yín sílẹ̀.” Mose bá pe Joṣua, ó sọ fún un níwájú gbogbo àwọn eniyan Israẹli, pé, “Múra gírí, kí o sì mú ọkàn gidigidi nítorí ìwọ ni o óo kó àwọn eniyan wọnyi lọ sí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun ti búra fún àwọn baba wọn pé òun yóo fi fún wọn. Ìwọ ni o óo sì fi lé wọn lọ́wọ́. OLUWA Ọlọrun tìkalárarẹ̀ ni yóo máa ṣiwaju rẹ lọ, yóo sì máa wà pẹlu rẹ. Kò ní já ọ kulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní fi ọ́ sílẹ̀. Má ṣe bẹ̀rù, má sì jẹ́ kí àyà fò ọ́.” Mose bá kọ òfin yìí sílẹ̀, ó fún àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ru àpótí majẹmu OLUWA ati gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli. Mose bá pàṣẹ fún wọn pé, “Ní ìparí ọdún keje-keje, ní àkókò tí a yà sọ́tọ̀ fún ọdún ìdásílẹ̀, ní àkókò àjọ̀dún àgọ́, nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá wá sin OLUWA ní ibi tí ó yàn pé kí wọ́n ti máa sin òun, o gbọdọ̀ máa ka òfin yìí sí etígbọ̀ọ́ gbogbo wọn. Pe àwọn eniyan náà jọ, ati ọkunrin ati obinrin, ati ọmọde ati àgbà, ati onílé ati àlejò, tí ó wà ninu ìlú yín, kí wọ́n lè gbọ́, kí wọ́n sì kọ́ láti bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín, kí wọ́n sì máa fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ tẹ̀lé gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí ó wà ninu òfin yìí. Kí àwọn ọmọ wọn tí kò tíì mọ̀ ọ́n lè gbọ́ nípa rẹ̀, kí wọ́n sì lè kọ́ láti bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín, níwọ̀n ìgbà tí ẹ bá wà lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń rékọjá lọ sí òkè odò Jọdani láti gbà.” OLUWA Ọlọrun sọ fún Mose pé, “Àkókò ń tó bọ̀ tí o óo kú, pe Joṣua, kí ẹ̀yin mejeeji wá sinu àgọ́ àjọ kí n lè fi ohun tí yóo ṣe lé e lọ́wọ́.” Mose ati Joṣua bá wọ inú àgọ́ àjọ lọ. OLUWA fi ara hàn wọ́n ninu ọ̀wọ̀n ìkùukùu ninu àgọ́ náà. Ọ̀wọ̀n ìkùukùu náà wà ní ẹ̀bá ẹnu ọ̀nà àgọ́. OLUWA tún sọ fún Mose pé, “Ọjọ́ àtisùn rẹ kù sí dẹ̀dẹ̀. Àwọn eniyan wọnyi yóo lọ máa bọ àwọn oriṣa tí àwọn ará ilẹ̀ náà ń bọ. Wọn óo kọ̀ mí sílẹ̀, wọn óo sì da majẹmu tí mo bá wọn dá. Inú mi yóo ru sí wọn ní ọjọ́ náà, èmi náà óo kọ̀ wọ́n sílẹ̀, n óo mú ojú mi kúrò lára wọn, n óo sì pa wọ́n run. Oríṣìíríṣìí ibi ati wahala ni yóo bá wọn, tóbẹ́ẹ̀ tí wọn yóo máa wí ní ọjọ́ náà pé, ‘Ǹjẹ́ nítorí pé kò sí Ọlọrun wa láàrin wa kọ́ ni gbogbo ibi wọnyi fi dé bá wa?’ Láìṣe àní àní, n óo mú ojú kúrò lára wọn ní ọjọ́ náà, nítorí gbogbo ibi tí wọ́n ti ṣe, nítorí pé wọ́n ti yipada, wọ́n sì ń bọ oriṣa. “Nítorí náà, kọ orin yìí sílẹ̀ nisinsinyii kí o sì kọ́ àwọn ọmọ Israẹli, kí orin náà lè jẹ́ ẹlẹ́rìí mi lọ́dọ̀ wọn. Nítorí pé, nígbà tí mo bá kó wọn wọ ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin, tí mo ti búra pé n óo fún àwọn baba wọn; nígbà tí wọ́n bá jẹ, tí wọ́n yó tán, tí wọ́n sì sanra, wọn óo yipada sọ́dọ̀ àwọn oriṣa, wọn óo sì máa bọ wọ́n. Wọn óo kọ̀ mí sílẹ̀, wọn óo sì da majẹmu mi. Nígbà tí ọpọlọpọ ibi ati wahala bá dé bá wọn, orin yìí ni yóo jẹ́ ẹ̀rí fún wọn (nítorí pé arọmọdọmọ wọn yóo máa kọ ọ́, wọn kò sì ní gbàgbé rẹ̀); nítorí pé mo mọ ète tí wọn ń pa, kí ó tilẹ̀ tó di pé mo mú wọn wọ ilẹ̀ tí mo búra láti fún wọn.” Mose bá kọ orin yìí ní ọjọ́ náà-gan an, ó sì kọ́ àwọn ọmọ Israẹli. OLUWA fi iṣẹ́ lé Joṣua ọmọ Nuni lọ́wọ́, ó ní, “Múra gírí kí o sì mú ọkàn gidigidi, nítorí ìwọ ni o óo kó àwọn ọmọ Israẹli wọ ilẹ̀ tí mo ti búra láti fún wọn. N óo wà pẹlu rẹ.” Nígbà tí Mose kọ gbogbo ohun tí ó wà ninu ìwé òfin yìí tán patapata, ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ru àpótí majẹmu OLUWA, ó ní, “Ẹ fi ìwé òfin yìí sí ẹ̀gbẹ́ àpótí majẹmu OLUWA Ọlọrun yín, kí ó wà níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pẹlu yín; nítorí mo mọ̀ pé ọlọ̀tẹ̀ ati olóríkunkun ni yín; nígbà tí mo wà láàyè pẹlu yín lónìí, ẹ̀ ń ṣọ̀tẹ̀ sí OLUWA, kí á má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ìgbà tí mo bá kú tán. Ẹ pe gbogbo àwọn àgbààgbà ẹ̀yà yín wá sọ́dọ̀ mi, ati gbogbo àwọn olórí ninu yín, kí àwọn náà lè máa gbọ́ bí mo ti ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, kí ẹ sì pe ọ̀run ati ayé láti ṣe ẹlẹ́rìí wọn. Nítorí mo mọ̀ dájú pé gẹ́rẹ́ tí mo bá kú tán, ìṣekúṣe ni ẹ óo máa ṣe, ẹ óo sì yipada kúrò ní ọ̀nà tí mo ti pa láṣẹ fun yín, ibi ni yóo sì ba yín ní ọjọ́ iwájú, nítorí pé ẹ óo ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA. Iṣẹ́ ọwọ́ yín yóo sì mú un bínú.” Mose ka gbogbo ọ̀rọ̀ orin náà patapata sí etígbọ̀ọ́ àpéjọ àwọn ọmọ Israẹli. Ó ní: “Tẹ́tísílẹ̀, ìwọ ọ̀run, mo fẹ́ sọ̀rọ̀; gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ, ìwọ ayé. Kí ẹ̀kọ́ mi kí ó máa rọ̀ bí òjò, àní, bí ọ̀wààrà òjò tíí dẹ ewébẹ̀ lọ́rùn; kí ó sì máa sẹ̀ bí ìrì, bí òjò wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ tíí tu koríko lára. Nítorí pé n óo polongo orúkọ OLUWA, àwọn eniyan rẹ yóo sì sọ nípa títóbi rẹ̀. “Pípé ni iṣẹ́ ọwọ́ OLUWA, àpáta ààbò yín, gbogbo ọ̀nà rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀tọ́. Olódodo ni Ọlọrun, ẹni tí kì í ṣe àṣìṣe, ẹ̀tọ́ ní í máa ń ṣe nígbà gbogbo. Ṣugbọn ẹ̀yin ọmọ Israẹli ti hu ìwà aiṣododo sí i, ẹ kò sì yẹ ní ẹni tí à bá máa pè ní ọmọ rẹ̀ mọ́, nítorí àbùkù yín; ẹ̀yin ìran ọlọ̀tẹ̀ ati ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí. Ṣé irú ohun tí ó yẹ kí ẹ fi san án fún OLUWA nìyí, ẹ̀yin ìran òmùgọ̀ ati aláìnírònú ẹ̀dá wọnyi? Ṣebí òun ni baba yín, tí ó da yín, Tí ó da yín tán, tí ó sì fi ìdí yín múlẹ̀. “Ẹ ranti ìgbà àtijọ́, ẹ ṣe akiyesi ọpọlọpọ ọdún tí ó ti kọjá. Ẹ bèèrè lọ́wọ́ baba yín, yóo fihàn yín, Ẹ bi àwọn àgbààgbà yín, wọn yóo sì sọ fun yín. Nígbà tí Ọlọrun ọ̀gá ògo pín ilẹ̀ ìní fún àwọn orílẹ̀-èdè, ó ṣètò ibi tí orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan yóo máa gbé, gẹ́gẹ́ bí ìdílé kọ̀ọ̀kan láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Nítorí pé ìpín OLUWA ni àwọn eniyan rẹ̀, ó yan àwọn ọmọ Jakọbu ní ohun ìní fún ara rẹ̀. “Ninu aṣálẹ̀ ni ó ti rí wọn, níbi tí kò sí igi tabi koríko, àfi kìkì yanrìn. Ó yí wọn ká, ó sì ń tọ́jú wọn, Ó sì dáàbò bò wọ́n bí ẹyin ojú rẹ̀. Bí ẹyẹ idì tií tú ìtẹ́ rẹ̀ ká, láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ bí à á tíí fò, tíí sì í na apá rẹ̀ láti hán wọn tí wọ́n bá fẹ́ já bọ́, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ń ṣe sí Israẹli. OLUWA nìkan ṣoṣo ni ó ṣáájú àwọn eniyan rẹ̀, láìsí ìrànlọ́wọ́ oriṣa kankan. “Ó fi wọ́n jọba lórí àwọn òkè ayé, ó sì fún wọn ní èso ilẹ̀ jẹ. Ó pèsè oyin fún wọn láti inú àpáta, ó sì mú kí igi olifi hù fún wọn lórí ilẹ̀ olókùúta. Wọn rí ọpọlọpọ wàrà lára mààlúù wọn, ati ọ̀pọ̀ omi wàrà lára ewúrẹ́ wọn, ó fún wọn ní ọ̀rá ọ̀dọ́ aguntan ati ti àgbò, ó fún wọn ní mààlúù Baṣani, ati ewúrẹ́, ati ọkà tí ó dára jùlọ, ati ọpọlọpọ ọtí waini. “Ṣugbọn ẹ̀yin ọmọ Jeṣuruni, ẹ yó tán, ẹ wá tàpá sí àṣẹ; ẹ rí jẹ, ẹ rí mu, ẹ sì lókun lára; ẹ wá gbàgbé Ọlọrun tí ó da yín, ẹ sì ń pẹ̀gàn àpáta ìgbàlà yín! Wọ́n fi ìbọ̀rìṣà wọn sọ OLUWA di òjòwú; wọ́n fi ìwà burúkú wọn mú kí ibinu OLUWA wọn ru sókè. Wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí rúbọ sí àwọn ẹ̀mí burúkú, Àwọn oriṣa tí wọn kò mọ̀ rí, tí àwọn baba wọn kò sì bọ rí. Ẹ gbàgbé àpáta ìgbàlà yín, ẹ gbàgbé Ọlọrun tí ó da yín. “Nígbà tí OLUWA rí ohun tí àwọn ọmọ rẹ̀ ń ṣe, ó kọ̀ wọ́n sílẹ̀, nítorí pé, wọ́n mú un bínú. Ó ní, ‘N óo mójú kúrò lára wọn, n óo sì máa wò bí ìgbẹ̀yìn wọn yóo ti rí. Nítorí olóríkunkun ni wọ́n, àwọn alaiṣootọ ọmọ! Nítorí oriṣa lásánlàsàn, wọn sọ èmi Ọlọrun di òjòwú; wọn sì ti fi àwọn ère wọn mú mi bínú. Nítorí náà, èmi náà óo lo àwọn eniyan lásánlàsàn láti mu àwọn náà jowú, n óo sì lo aṣiwèrè orílẹ̀-èdè lásánlàsàn kan láti mú wọn bínú. Nítorí iná ibinu mi ń jó, yóo sì jó títí dé isà òkú. Yóo jó ayé ati ohun gbogbo tí ń bẹ ninu rẹ̀ ní àjórun, tó fi mọ́ ìpìlẹ̀ àwọn òkè ńlá. “ ‘N óo da oríṣìíríṣìí ibi sórí wọn, n óo sì rọ òjò ọfà mi sára wọn. N óo fi ebi pa wọ́n ní àpakú, iná yóo jó wọn ní àjórun, n óo sì fi àjàkálẹ̀ àrùn pa wọ́n run. N óo jẹ́ kí àwọn ẹranko burúkú pa wọ́n jẹ, n óo sì jẹ́ kí àwọn ejò olóró bù wọ́n ṣán. Bí idà tí ń pa àwọn kan lójú pópó, bẹ́ẹ̀ ni ikú yóo di ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ láàrin ọ̀dẹ̀dẹ̀. Bó ti ń pa àwọn ọdọmọkunrin, bẹ́ẹ̀ ni yóo máa pa àwọn ọdọmọbinrin, ati àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ ati àwọn arúgbó kùjọ́kùjọ́, gbogbo wọn ni ikú gbígbóná yóo máa mú lọ. Ǹ bá wí pé kí n fọ́n wọn káàkiri, kí ẹnikẹ́ni má tilẹ̀ ranti wọn mọ́, ti àwọn ọ̀tá wọn ni mo rò, nítorí pé, ọ̀tọ̀ ni ohun tí wọn yóo máa wí kiri. Wọn yóo máa wí pé, “Àwa ni a ṣẹgun wọn, kìí ṣe OLUWA ló ṣe é rárá.” ’ “Nítorí pé aláìlérò orílẹ̀-èdè ni Israẹli, òye kò sì yé wọn rárá. Bí ó bá ṣe pé wọ́n gbọ́n ni, tí òye sì yé wọn; wọn ì bá ti mọ̀ bí ìgbẹ̀yìn wọn yóo ti rí. Ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo ṣe lè lé ẹgbẹrun eniyan? Àní, eniyan meji péré ṣe lè lé ẹgbaarun eniyan sá? Bí kò bá jẹ́ pé Ọlọrun aláàbò wọn ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀, tí OLUWA sì ti fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́. Nítorí pé, àwọn ọ̀tá wọn pàápàá mọ̀ pé, Ọlọrun, aláàbò Israẹli, kì í ṣe ẹgbẹ́ àwọn oriṣa wọn. Àwọn ọ̀tá wọn ti bàjẹ́ bíi Sodomu ati Gomora, wọ́n dàbí àjàrà tí ń so èso tí ó korò tí ó sì lóró. Oró ejò ni ọtí wọn, àní oró paramọ́lẹ̀ tíí ṣe ikú pani. “Èmi OLUWA kò gbàgbé ohun tí àwọn ọ̀tá wọn ṣe, ṣebí gbogbo rẹ̀ wà ní àkọsílẹ̀ lọ́dọ̀ mi? Èmi OLUWA ni ẹlẹ́san, n óo sì gbẹ̀san, nítorí ọjọ́ ń bọ̀, tí àwọn pàápàá yóo yọ̀ ṣubú. Ọjọ́ ìdààmú wọn kù sí dẹ̀dẹ̀, ọjọ́ ìparun wọn sì ń bọ̀ kíákíá. Nítorí pé, OLUWA yóo dá àwọn eniyan rẹ̀ láre, yóo sì ṣàánú fún àwọn iranṣẹ rẹ̀, nígbà tí ó bá rí i pé wọn kò lágbára mọ́, ati pé kò sí olùrànlọ́wọ́ fún wọn, tí kò sì ṣẹ́ku ẹnìkan ninu wọn, kì báà ṣe ẹrú tabi òmìnira. Nígbà náà ni yóo bi wọ́n pé, ‘Níbo ni àwọn oriṣa yin wà, ati àpáta tí ẹ fi ṣe ààbò yin? Ṣebí àwọn ni ẹ fún ní ọ̀rá ẹran ìrúbọ yín, àwọn ni ẹ sì rú ẹbọ ohun mímu yín sí? Kí wọ́n dìde, kí wọ́n ràn yín lọ́wọ́ nisinsinyii, kí wọ́n sì dáàbò bò yín. “ ‘Ṣé ẹ wá rí i nisinsinyii pé, èmi nìkan ṣoṣo ni Ọlọrun, kò sí ọlọrun mìíràn mọ, lẹ́yìn mi. Mo lè pa eniyan, mo sì lè sọ ọ́ di ààyè. Mo lè ṣá eniyan lọ́gbẹ́, mo sì lè wò ó sàn. Bí mo bá gbá eniyan mú, kò sí ẹni tí ó lè gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ mi. Níwọ̀n bí mo ṣe jẹ́ Ọlọrun alààyè, mo fi ara mi búra. Nígbà tí mo bá pọ́n idà mi, tí ó ń kọ yànrànyànràn, n óo fà á yọ láti fi ṣe ẹ̀tọ́. N óo gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi, n óo sì jẹ àwọn tí wọ́n kórìíra mi níyà. Ọfà mi yóo tẹnu bọ ẹ̀jẹ̀, yóo sì mu àmuyó. Idà mi yóo sì bẹ́ gbogbo àwọn tí wọ́n lòdì sí mi. N kò ni dá ẹnikẹ́ni sí, ninu àwọn tí wọ́n gbógun tì mí, ati àwọn tí wọ́n ti fara gbọgbẹ́, ati àwọn tí wọ́n dì nígbèkùn, gbogbo wọn ni n óo pa.’ “Ẹ máa yìn ín ẹ̀yin eniyan OLUWA, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, nítorí pé yóo gbẹ̀san lára àwọn tí wọ́n bá pa àwọn iranṣẹ rẹ̀. Yóo sì jẹ àwọn ọ̀tá rẹ̀ níyà, yóo sì ṣe ètùtù fún ilẹ̀ àwọn eniyan rẹ̀.” Mose wá, ó sì ka gbogbo ọ̀rọ̀ orin yìí sí etígbọ̀ọ́ àwọn eniyan náà, òun ati Joṣua ọmọ Nuni. Nígbà tí Mose bá àwọn ọmọ Israẹli sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi tán, ó ní, “Ẹ fi gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ba yín sọ lónìí sọ́kàn, kí ẹ sì pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ yín, kí wọ́n lè pa gbogbo òfin wọnyi mọ́ lẹ́sẹẹsẹ. Nítorí pé kìí ṣe nǹkan yẹpẹrẹ ni, òun ni ẹ̀mí yín. Bí ẹ bá pa á mọ́, ẹ óo wà láàyè, ẹ óo sì pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń rékọjá Jọdani lọ gbà.” OLUWA sọ fún Mose ní ọjọ́ náà gan-an pé, “Lọ sí òkè Abarimu tí ó dojú kọ ìlú Jẹriko, ní ilẹ̀ Moabu. Gun orí òkè Nebo lọ, kí o sì wo gbogbo ilẹ̀ Kenaani tí mo fún àwọn eniyan Israẹli. Orí òkè Nebo yìí ni o óo kú sí, bí Aaroni arakunrin rẹ ṣe kú lórí òkè Hori. Nítorí pé, ẹ̀yin mejeeji ni ẹ kò hùwà òtítọ́ sí mi láàrin àwọn ọmọ Israẹli, nígbà tí ẹ wà ní odò Meriba Kadeṣi, ní aṣálẹ̀ Sini. Ẹ tàbùkù mi lójú gbogbo àwọn eniyan, ẹ kò bọ̀wọ̀ fún mi gẹ́gẹ́ bí ẹni mímọ́ níwájú àwọn eniyan náà. Nítorí náà, o óo fi ojú rí ilẹ̀ náà, ṣugbọn ẹsẹ̀ rẹ kò ní tẹ ilẹ̀ tí n ó fún àwọn eniyan Israẹli.” Ìre tí Mose eniyan Ọlọrun sú fún àwọn ọmọ Israẹli kí ó tó kú nìyí. Ó ní: OLUWA wá láti orí òkè Sinai, ó yọ gẹ́gẹ́ bí oòrùn láti Edomu, ó ràn sórí àwọn eniyan rẹ̀ láti òkè Parani. Ó wá láti ọ̀dọ̀ ẹgbaarun àwọn ẹni mímọ́, ó gbé iná tí ń jò lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀. Ọlọrun fẹ́ràn àwọn eniyan rẹ̀, gbogbo àwọn tí a yà sọ́tọ̀ fún un wà lọ́wọ́ rẹ̀, nítorí náà ni wọ́n ṣe ń tẹ̀lé ọ̀nà rẹ̀, tí wọ́n sì ń gba àṣẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, nígbà tí Mose bá fún wa ní òfin, tí ó jẹ́ ohun ìní gbogbo eniyan Israẹli. Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe di ọba ní Jeṣuruni, nígbà tí gbogbo àwọn olórí péjọ, àní, gbogbo àwọn olórí ninu ẹ̀yà Israẹli. Mose súre fún ẹ̀yà Reubẹni, ó ní: “Ẹ̀yà Reubẹni yóo máa wà ni, kò ní parun, àwọn eniyan rẹ̀ kò ní dínkù.” Ó súre fún ẹ̀yà Juda pé: “OLUWA, gbọ́ igbe ẹ̀yà Juda, nígbà tí wọ́n bá pè fún ìrànwọ́, sì kó wọn pada sọ́dọ̀ àwọn eniyan wọn. Fi ọwọ́ ara rẹ jà fún wọn, sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí àwọn ọ̀tá wọn.” Ó súre fún ẹ̀yà Lefi pé: “OLUWA, fún Lefi, ẹni tíí ṣe olódodo, ní Tumimu ati Urimu rẹ; Lefi, tí o dánwò ní Masa, tí o sì bá jà níbi odò tí ó wà ní Meriba; àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn kò ka òbí àwọn sí, ju ìwọ OLUWA lọ; wọ́n kọ àwọn arakunrin wọn sílẹ̀, wọ́n sì ṣá àwọn ọmọ wọn tì. Nítorí pé wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, wọ́n sì ń pa majẹmu rẹ mọ́. Wọn óo kọ́ ilé Jakọbu ní ìlànà rẹ, wọn óo sì kọ́ àwọn ọmọ Israẹli ní òfin rẹ. Àwọn ni wọn óo máa sun turari níbi ẹbọ rẹ, wọn óo sì máa rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ rẹ. OLUWA, bukun àwọn ohun ìní wọn, sì jẹ́ kí iṣẹ́ ọwọ́ wọn jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lójú rẹ, Fọ́ egungun itan àwọn ọ̀tá wọn, tẹ̀ wọ́n ní àtẹ̀rẹ́, kí àwọn tí wọ́n bá kórìíra wọn má sì lè gbérí mọ́.” Ó súre fún ẹ̀yà Bẹnjamini pé: “Bẹnjamini, ẹ̀yà tí OLUWA fẹ́ràn tí ó sì ń dáàbò bò, OLUWA ń ṣọ́ wọn nígbà gbogbo, ó sì ń gbé ààrin wọn.” Ó súre fún ẹ̀yà Josẹfu pé: “Kí OLUWA rọ òjò ibukun sórí ilẹ̀ wọn, kí ó sì bu omi rin ín láti abẹ́ ilẹ̀ wá. Kí OLUWA pèsè ọpọlọpọ èso sórí ilẹ̀ wọn, kí ó sì kún fún àwọn èso tí ó dára jùlọ láti ìgbà dé ìgbà. Kí àwọn òkè ńláńlá àtijọ́ so ọpọlọpọ èso dáradára, kí ọpọlọpọ èso sì bo àwọn òkè kéékèèké. Kí ilẹ̀ wọn kún fún oríṣìíríṣìí àwọn ohun tí ó dára, pẹlu ibukun láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ń gbé inú pápá tí ń jó. Kí ó wá sórí Josẹfu, àní, sórí ẹni tó jẹ́ aṣiwaju fún àwọn arakunrin rẹ̀. Àkọ́bí rẹ̀ lágbára bí akọ mààlúù, Ìwo rẹ̀ sì dàbí ìwo mààlúù tí ó lágbára, tí yóo fi máa ti àwọn orílẹ̀-èdè títí dé òpin ayé. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹgbẹẹgbaarun àwọn ọmọ Efuraimu, ati ẹgbẹẹgbẹrun àwọn ọmọ Manase.” Ó súre fún Sebuluni ati fún Isakari, ó ní: “Máa yọ̀ bí o ti ń jáde lọ, ìwọ Sebuluni, sì máa yọ̀ ninu ilé rẹ, ìwọ Isakari. Wọn óo pe àwọn àlejò jọ sórí òkè, wọn óo sì máa rú ẹbọ ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ níbẹ̀. Nítorí wọn óo máa kó ọrọ̀ jọ láti inú òkun, ati dúkìá tí ó farasin láti inú yanrìn etí òkun.” Ìre tí ó sú fún ẹ̀yà Gadi ni pé: “Ibukun ni fún ẹni tí ó bukun ilẹ̀ Gadi, Gadi dàbí kinniun tí ó ba láti fani lápá ya, ati láti géni lórí. Ibi tí ó dára jùlọ ninu ilẹ̀ náà ni wọ́n mú fún ara wọn, nítorí pé ibẹ̀ ni ìpín olórí ogun wà, ó wá sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí àwọn eniyan náà, àtòun, àtàwọn eniyan náà sì ń pa àṣẹ OLUWA mọ́, wọn sì ń ṣe ìdájọ́ òdodo.” Ó súre fun ẹ̀yà Dani pé: “Dani dàbí ẹgbọ̀rọ̀ kinniun, tí ó fò jáde láti Baṣani.” Ó súre fún ẹ̀yà Nafutali pé: “OLUWA ti ṣíjú rere wo Nafutali, ó sì ti bukun un lọpọlọpọ, ilẹ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ láti adágún Galili, títí lọ kan gúsù gbọ̀ngbọ̀n.” Ìre tí ó sú fún ẹ̀yà Aṣeri ni pé: “Ibukun ẹ̀yà Aṣeri ta gbogbo ibukun ẹ̀yà yòókù yọ, àyànfẹ́ ni yóo jẹ́ láàrin àwọn arakunrin rẹ̀, ilẹ̀ rẹ̀ yóo sì kún fún òróró olifi. Ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn rẹ̀ yóo jẹ́ irin ati idẹ, bí iye ọjọ́ orí rẹ̀ bá ti tó, bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ yóo pọ̀ tó.” Ẹ̀yin ará Jeṣuruni, kò sí ẹni tí ó dàbí Ọlọrun yín, tí ó gun awọsanma lẹ́ṣin ninu ọlá ńlá rẹ̀, láti wá ràn yín lọ́wọ́. Ọlọrun ayérayé ni ààbò yín, ọwọ́ rẹ̀ ni ó sì fi ń gbé yín ró. Bí ẹ ti ń súnmọ́ wájú, bẹ́ẹ̀ ni ó ń lé àwọn ọ̀tá yín jáde, tí ó sì ní kí ẹ máa pa wọ́n run. Nítorí náà, Israẹli wà ní alaafia, àwọn ọmọ Jakọbu sì ń gbé láìléwu, ní ilẹ̀ tí ó kún fún ọkà ati ọtí waini, tí ìrì sì ń sẹ̀ sórí rẹ̀ láti ọ̀run wá. Ẹ máa fò fún ayọ̀, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ta ló tún dàbí yín, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè tí OLUWA tìkalárarẹ̀ gbàlà? OLUWA tìkalárarẹ̀ ni ààbò yín, ati idà yín, òun ní ń dáàbò bò yín, tí ó sì ń fun yín ní ìṣẹ́gun. Àwọn ọ̀tá yín ni yóo máa wá bẹ̀bẹ̀ fún àánú, ẹ óo sì máa tẹ àwọn pẹpẹ ìrúbọ wọn mọ́lẹ̀. Mose gbéra láti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, ó gun orí òkè Nebo lọ títí dé ṣóńṣó òkè Pisiga, tí ó wà ní òdìkejì Jẹriko. OLUWA sì fi gbogbo ilẹ̀ náà hàn án láti Gileadi lọ, títí dé Dani, gbogbo ilẹ̀ Nafutali, ilẹ̀ Efuraimu, ilẹ̀ Manase, ati gbogbo ilẹ̀ Juda, títí dé etí òkun ìwọ̀ oòrùn, ilẹ̀ Nẹgẹbu ni apá gúsù ati gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí ó wà ní àfonífojì Jẹriko, ìlú tí ó kún fún ọ̀pẹ, títí dé ilẹ̀ Soari. OLUWA wí fún un pé, “Ilẹ̀ tí mo búra fún Abrahamu, ati fún Isaaki, ati fún Jakọbu pé, n óo fi fún àwọn arọmọdọmọ wọn nìyí, mo jẹ́ kí o rí i, ṣugbọn o kò ní dé ibẹ̀.” Mose iranṣẹ OLUWA kú ní ilẹ̀ Moabu gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA. OLUWA sin ín sí àfonífojì ilẹ̀ Moabu tí ó dojú kọ Betipeori, ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò mọ ibojì rẹ̀ títí di òní olónìí. Mose jẹ́ ẹni ọgọfa (120) ọdún nígbà tí ó kú, ojú rẹ̀ kò ṣe bàìbàì, bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ kò dínkù. Àwọn ọmọ Israẹli ṣọ̀fọ̀ Mose fún ọgbọ̀n ọjọ́ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, wọ́n sì parí ṣíṣe òkú rẹ̀. Joṣua ọmọ Nuni kún fún ọgbọ́n nítorí pé Mose ti gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e, nítorí náà àwọn ọmọ Israẹli ń gbọ́ tirẹ̀, wọ́n sì ń ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún Mose. Láti ìgbà náà, kò tíì sí wolii mìíràn ní ilẹ̀ Israẹli tí ó dàbí Mose, ẹni tí Ọlọrun bá sọ̀rọ̀ lojukooju. Kò sì sí ẹlòmíràn tí OLUWA rán láti ṣe ọpọlọpọ iṣẹ́ ìyanu lára Farao ati gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati gbogbo ilẹ̀ rẹ̀, ní ilẹ̀ Ijipti. Bẹ́ẹ̀ ni kò sí wolii mìíràn tí ó ní agbára ńlá tabi tí ó ṣe àwọn ohun tí ó bani lẹ́rù bí Mose ti ṣe lójú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli. Lẹ́yìn ikú Mose, iranṣẹ OLUWA, OLUWA sọ fún Joṣua, ọmọ Nuni, olùrànlọ́wọ́ Mose pé, “Mose iranṣẹ mi ti kú, nítorí náà, ìwọ ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ẹ múra kí ẹ la odò Jọdani kọjá, kí ẹ sì wọ ilẹ̀ tí n óo fun yín. Gbogbo ibi tí ẹsẹ̀ yín bá tẹ̀ ni mo ti fun yín, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣèlérí fún Mose. Láti inú aṣálẹ̀ ati òkè Lẹbanoni yìí lọ, títí dé odò ńlá náà, odò Yufurate, gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Hiti, títí dé Òkun Mẹditarenia ní apá ìwọ̀ oòrùn, ni yóo jẹ́ ilẹ̀ yín. Kò ní sí ẹni tí yóo lè borí rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. Bí mo ti wà pẹlu Mose ni n óo wà pẹlu rẹ. N kò ní já ọ kulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lae. Múra, kí o sì ṣe ọkàn gírí, nítorí ìwọ ni o óo jẹ́ kí àwọn eniyan wọnyi gba ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba wọn, pé n óo fún wọn. Ìwọ ṣá ti múra, kí o ṣe ọkàn gírí, kí o sì rí i dájú pé o pa gbogbo òfin tí Mose, iranṣẹ mi, fún ọ mọ́. Má ṣe yẹsẹ̀ kúrò ninu rẹ̀ sí ọ̀tún, tabi sí òsì, kí gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ lé níbikíbi tí o bá lọ lè máa yọrí sí rere. Máa ka ìwé òfin yìí nígbà gbogbo, kí o sì máa ṣe àṣàrò ninu rẹ̀, tọ̀sán-tòru; rí i dájú pé o pa gbogbo ohun tí wọ́n kọ sinu rẹ̀ mọ́. Nígbà náà ni yóo dára fún ọ, gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ lé yóo sì máa yọrí sí rere. Ranti pé mo ti pàṣẹ fún ọ pé kí o múra, kí o sì ṣe ọkàn gírí. Má bẹ̀rù, má sì jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn rẹ, nítorí pé èmi, OLUWA Ọlọrun rẹ wà pẹlu rẹ níbikíbi tí o bá ń lọ.” Lẹ́yìn náà, Joṣua pàṣẹ fún gbogbo àwọn olórí àwọn eniyan náà, ó ní, “Ẹ lọ káàkiri ibùdó, kí ẹ sì pàṣẹ fún àwọn eniyan náà, pé kí wọn máa pèsè oúnjẹ sílẹ̀, nítorí pé láàrin ọjọ́ mẹta wọn óo la odò Jọdani kọjá láti lọ gba ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun wọn fún wọn.” Joṣua sọ fún àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ati ti Gadi, ati ìdajì ẹ̀yà Manase pé, “Ẹ ranti àṣẹ tí Mose, iranṣẹ OLUWA, pa fun yín pé, ‘OLUWA Ọlọrun yín ń pèsè ibi ìsinmi fun yín, yóo sì fi ilẹ̀ yìí fun yín.’ Àwọn aya yín, àwọn ọmọ yín kéékèèké, ati àwọn ẹran ọ̀sìn yín ni yóo kù lẹ́yìn lórí ilẹ̀ tí Mose fun yín ní òdìkejì odò Jọdani; ṣugbọn gbogbo àwọn akọni láàrin yín yóo rékọjá sí òdìkejì odò náà pẹlu ihamọra ogun níwájú àwọn arakunrin yín, wọn yóo máa ràn wọ́n lọ́wọ́ títí tí OLUWA yóo fi fún àwọn arakunrin yín ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó ti fun yín, tí wọn yóo sì fi gba ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fún wọn. Nígbà náà ni ẹ óo tó pada sí orí ilẹ̀ yín, tí Mose, iranṣẹ OLUWA, fun yín ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani, ẹ óo sì máa gbé ibẹ̀.” Wọ́n dá Joṣua lóhùn pé, “Gbogbo ohun tí o pa láṣẹ fún wa ni a óo ṣe, ibikíbi tí o bá sì rán wa ni a óo lọ. Bí a ti gbọ́ ti Mose, bẹ́ẹ̀ ni a óo máa gbọ́ tìrẹ náà. Kí OLUWA Ọlọrun rẹ ṣá ti wà pẹlu rẹ gẹ́gẹ́ bí ó ti wà pẹlu Mose. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tàpá sí àṣẹ rẹ, tí ó sì kọ̀ láti ṣe ohunkohun tí o bá sọ fún un, pípa ni a óo pa á. Ìwọ ṣá ti múra, kí o sì ṣe ọkàn gírí.” Lẹ́yìn náà, Joṣua ọmọ Nuni rán amí meji láti Akasia, lọ sí Jẹriko, ó ní, “Ẹ lọ wo ilẹ̀ náà, pàápàá jùlọ, ìlú Jẹriko.” Wọ́n bá lọ, wọ́n sì dé sí ilé aṣẹ́wó kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Rahabu. Àwọn kan bá lọ sọ fún ọba Jẹriko pé, “Àwọn ọkunrin kan, lára àwọn ọmọ Israẹli, wá sí ibí ní alẹ́ yìí láti ṣe amí ilẹ̀ yìí.” Ọba Jẹriko bá ranṣẹ sí Rahabu ó ní, “Kó àwọn ọkunrin tí wọn dé sọ́dọ̀ rẹ jáde wá, nítorí pé wọ́n wá ṣe amí ilẹ̀ yìí ni.” Ṣugbọn obinrin náà ti kó àwọn ọkunrin mejeeji pamọ́, ó dáhùn pé, “Lóòótọ́ ni àwọn ọkunrin meji kan wá sọ́dọ̀ mi, ṣugbọn n kò mọ ibi tí wọn ti wá. Nígbà tí ilẹ̀ ń ṣú lọ tí ó kù díẹ̀ kí wọ́n ti ìlẹ̀kùn ẹnu ibodè ni wọ́n jáde lọ, n kò sì mọ ibi tí wọ́n lọ. Ẹ tètè máa lépa wọn lọ, ẹ óo bá wọn lọ́nà.” Ṣugbọn ó ti kó wọn gun orí òrùlé rẹ̀, ó sì ti fi wọ́n pamọ́ sáàrin pòpórò igi ọ̀gbọ̀ tí ó tò jọ sibẹ. Àwọn tí ọba rán bá bẹ̀rẹ̀ sí lépa àwọn ọkunrin náà lọ ní ọ̀nà odò Jọdani, títí dé ibi tí ọ̀nà ti rékọjá odò náà, bí àwọn tí ọba rán ti jáde ní ìlú, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ti ìlẹ̀kùn odi ìlú náà. Kí àwọn amí meji náà tó sùn, Rahabu gun òrùlé lọ bá wọn, ó ní, “Mo mọ̀ pé OLUWA ti fi ilẹ̀ yìí lé e yín lọ́wọ́, jìnnìjìnnì yín ti bò wá, ẹ̀rù yín sì ti ń ba gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ yìí. Nítorí a ti gbọ́ bí OLUWA ti mú kí Òkun Pupa gbẹ níwájú yín nígbà tí ẹ jáde ní Ijipti, a sì ti gbọ́ ohun tí ẹ ṣe sí Sihoni ati Ogu, àwọn ọba ará Amori mejeeji tí wọ́n wà ní òkè odò Jọdani, bí ẹ ṣe pa wọ́n run patapata. Bí a ti gbọ́ ni jìnnìjìnnì ti bò wá, ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn sì ti bá gbogbo eniyan nítorí yín, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín ni Ọlọrun ọ̀run ati ayé. Nítorí náà, ẹ fi OLUWA búra fún mi nisinsinyii pé, bí mo ti ṣe yín lóore yìí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà yóo ṣe ilé baba mi lóore, kí ẹ sì fún mi ní àmì tí ó dájú. Kí ẹ dá baba mi ati ìyá mi sí, ati àwọn arakunrin mi, ati àwọn arabinrin mi, ati gbogbo àwọn eniyan wọn; ẹ má jẹ́ kí á kú.” Àwọn ọkunrin náà bá dá a lóhùn pé, “Kí OLUWA gba ẹ̀mí wa bí a bá pa yín. Bí o kò bá ṣá ti sọ ohun tí a wá ṣe níhìn-ín fún ẹnikẹ́ni, a óo ṣe ọ́ dáradára, a óo sì jẹ́ olóòótọ́ sí ọ nígbà tí OLUWA bá fi ilẹ̀ náà lé wa lọ́wọ́.” Ó bá fi okùn kan sọ̀ wọ́n kalẹ̀ láti ojú fèrèsé, nítorí pé àkọ́pọ̀ mọ́ odi ìlú ni wọ́n kọ́ ilé rẹ̀, inú odi yìí ni ó sì ń gbé. Ó bá kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ sá lọ sí orí òkè, kí àwọn tí wọ́n ń lépa yín má baà pàdé yín lójú ọ̀nà. Ẹ sá pamọ́ fún ọjọ́ mẹta, títí tí wọn óo fi pada dé. Lẹ́yìn náà, ẹ máa bá tiyín lọ.” Àwọn ọkunrin náà sọ fún Rahabu pé, “A óo mú ìlérí tí o mú kí á fi ìbúra ṣe fún ọ ṣẹ. Nígbà tí a bá wọ ilẹ̀ yìí, mú okùn pupa yìí, kí o so ó mọ́ ibi fèrèsé tí o ti sọ̀ wá kalẹ̀. Kó baba, ati ìyá rẹ, ati àwọn arakunrin rẹ, ati gbogbo àwọn ará ilé baba rẹ sí inú ilé rẹ. Bí ẹnikẹ́ni bá jáde kúrò ninu ilé rẹ lọ sí ààrin ìlú, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà lórí ara rẹ̀, kò sì ní sí ẹ̀bi lọ́rùn wa. Ṣugbọn bí wọn bá pa ẹnikẹ́ni ninu àwọn tí wọ́n wà ninu ilé pẹlu rẹ, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà lórí wa. Ṣugbọn bí o bá sọ ohun tí a wá ṣe fún ẹnikẹ́ni, ẹ̀bi ìlérí tí a fi ìbúra ṣe yìí kò ní sí lórí wa mọ́.” Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Bí ẹ ti wí gan-an, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí.” Ó ní kí wọ́n máa lọ, wọ́n sì lọ; ó bá so okùn pupa náà mọ́ fèrèsé rẹ̀. Wọ́n kúrò níbẹ̀, wọ́n sá lọ sí orí òkè, wọ́n sì farapamọ́ fún ọjọ́ mẹta, títí tí àwọn tí wọn ń lépa wọn fi pada; nítorí pé wọ́n ti wá wọn káàkiri títí ní gbogbo ojú ọ̀nà, wọn kò sì rí wọn. Àwọn ọkunrin meji náà sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, wọ́n lọ bá Joṣua, ọmọ Nuni, wọ́n bá sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn fún un. Wọ́n sọ fún Joṣua pé, “Láìṣe àní àní, OLUWA ti fi ilẹ̀ náà lé wa lọ́wọ́, ìdààmú ọkàn sì ti bá gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà nítorí wa.” Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli gbéra ní Akasia lọ sí etí odò Jọdani, wọ́n sì pàgọ́ níbẹ̀ kí wọn tó la odò náà kọjá. Lẹ́yìn ọjọ́ kẹta, gbogbo àwọn olórí wọn lọ káàkiri àgọ́ náà. Wọ́n pàṣẹ fún àwọn eniyan náà pé, “Nígbà tí ẹ bá rí i pé, àwọn alufaa, ọmọ Lefi gbé Àpótí Majẹmu OLUWA Ọlọrun yín, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ, kí ẹ̀yin náà gbéra, kí ẹ sì tẹ̀lé wọn. Kí ẹ lè mọ ọ̀nà tí ẹ óo gbà, nítorí pé ẹ kò rin ọ̀nà yìí rí. Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ súnmọ́ Àpótí Majẹmu náà jù, ẹ gbọdọ̀ fi àlàfo tí ó tó nǹkan bí ẹgbaa (2,000) igbọnwọ sílẹ̀ láàrin ẹ̀yin ati Àpótí Majẹmu náà.” Joṣua sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ ya ara yín sí mímọ́ nítorí pé OLUWA yóo ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrin yín ní ọ̀la.” Joṣua bá sọ fún àwọn alufaa pé, “Ẹ gbé Àpótí Majẹmu náà kí ẹ sì máa lọ níwájú àwọn eniyan yìí.” Wọ́n bá gbé Àpótí Majẹmu náà, wọ́n sì ń lọ níwájú wọn. OLUWA sọ fún Joṣua pé, “Lónìí ni n óo bẹ̀rẹ̀ sí gbé ọ ga lójú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, kí wọ́n lè mọ̀ pé bí mo ti wà pẹlu Mose, bẹ́ẹ̀ ni n óo wà pẹlu rẹ. Pàṣẹ fún àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu náà pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé etí odò Jọdani, ẹ wọ inú odò lọ, kí ẹ sì dúró níbẹ̀.’ ” Joṣua bá pe àwọn ọmọ Israẹli jọ, ó wí fún wọn pé, “Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA Ọlọrun yín wí. Èyí ni ẹ óo fi mọ̀ pé Ọlọrun alààyè wà láàrin yín, kò sì ní kùnà láti lé àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti, àwọn ará Hifi, àwọn ará Perisi, àwọn ará Girigaṣi, àwọn ará Amori, ati àwọn ará Jebusi, jáde fun yín. Wò ó! Wọn yóo gbé Àpótí Majẹmu OLUWA gbogbo ayé kọjá níwájú yín sinu odò Jọdani. Nítorí náà, ẹ yan àwọn ọkunrin mejila ninu ẹ̀yà Israẹli, ẹnìkọ̀ọ̀kan láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Nígbà tí ẹsẹ̀ àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu OLUWA gbogbo ayé bá kan odò Jọdani, odò náà yóo dúró; kò ní ṣàn mọ́, gbogbo omi tí ń ṣàn bọ̀ láti òkè yóo sì wọ́jọ pọ̀ bí òkítì ńlá.” Nígbà náà ni àwọn eniyan náà gbéra ninu àgọ́ wọn láti la odò Jọdani kọjá pẹlu àwọn alufaa tí wọn ń gbé Àpótí Majẹmu lọ níwájú wọn, (àkókò náà jẹ́ àkókò ìkórè, odò Jọdani sì kún dé ẹnu), ṣugbọn bí àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu ti dé etídò náà, tí wọ́n sì fi ẹsẹ̀ wọn kan omi, omi tí ń ṣàn bọ̀ láti òkè dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wọ́jọ pọ̀ bí òkítì ńlá ní òkèèrè ní ìlú Adamu tí ó wà lẹ́bàá Saretani. Èyí tí ó ń ṣàn lọ sí Òkun Araba tí à ń pè ní Òkun Iyọ̀ gé kúrò, ó sì dá dúró. Àwọn eniyan náà rékọjá sí òdìkejì ìlú Jẹriko. Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ń kọjá lọ lórí ilẹ̀ gbígbẹ, àwọn alufaa tí wọ́n ru Àpótí Majẹmu OLUWA dúró lórí ilẹ̀ gbígbẹ láàrin odò Jọdani, títí tí gbogbo àwọn eniyan náà fi la odò Jọdani kọjá. Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan náà rékọjá sí òdìkejì odò Jọdani tán, OLUWA wí fún Joṣua pé, “Yan ọkunrin mejila láàrin àwọn eniyan náà, ẹnìkọ̀ọ̀kan láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Kí o pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n gbé òkúta mejila láàrin odò Jọdani yìí, lọ́gangan ibi tí àwọn alufaa dúró sí, kí wọ́n gbé wọn lọ́wọ́ bí ẹ ti ń lọ, kí ẹ sì kó wọn jọ sí ibi tí ẹ óo sùn lálẹ́ òní.” Joṣua bá pe àwọn ọkunrin mejila tí ó ti yàn tẹ́lẹ̀ ninu àwọn ọmọ Israẹli, ẹnìkọ̀ọ̀kan láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan; ó wí fún wọn pé, “Ẹ kọjá lọ níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA Ọlọrun yín, sí ààrin odò Jọdani, kí ẹnìkọ̀ọ̀kan sì gbé òkúta kọ̀ọ̀kan lé èjìká rẹ̀. Kí iye òkúta tí ẹ óo gbé jẹ́ iye ẹ̀yà tí ó wà ninu àwọn ọmọ Israẹli. Kí èyí lè jẹ́ ohun ìrántí fun yín, nígbà tí àwọn ọmọ yín bá bèèrè lọ́wọ́ yín ní ọjọ́ iwájú pé, ‘Báwo ni ti àwọn òkúta wọnyi ti jẹ́ rí?’ Nígbà náà, ẹ óo dá wọn lóhùn pé omi odò Jọdani pín sí meji níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA nígbà tí wọn gbé e kọjá odò náà. Nítorí náà, àwọn òkúta wọnyi yóo jẹ́ ohun ìrántí ayérayé fún àwọn ọmọ Israẹli.” Àwọn ọkunrin náà ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Joṣua pa fún wọn. Wọ́n gbé òkúta mejila láti inú odò Jọdani, gẹ́gẹ́ bí iye ẹ̀yà tí ó wà ninu àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ fún Joṣua. Wọ́n gbé wọn lọ́wọ́ lọ sí ibi tí wọ́n sùn ní alẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n sì tò wọ́n jọ sibẹ. Joṣua to òkúta mejila mìíràn jọ láàrin odò Jọdani lọ́gangan ibi tí àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu dúró sí; àwọn òkúta náà wà níbẹ̀ títí di òní olónìí. Nítorí pé àwọn alufaa tí ó gbé Àpótí Majẹmu OLUWA dúró láàrin odò Jọdani, títí tí àwọn eniyan náà fi ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ pé kí Joṣua sọ fún wọn, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ fún un. Aré ni àwọn eniyan náà sá gun òkè odò Jọdani. Lẹ́yìn tí gbogbo wọn ti gun òkè odò tan, àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu OLUWA gòkè odò tẹ̀lé wọn, wọ́n sì rékọjá lọ siwaju wọn. Àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ati ẹ̀yà Gadi, ati ìdajì ẹ̀yà Manase náà gòkè odò pẹlu ihamọra ogun níwájú àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ fún wọn. Nǹkan bíi ọ̀kẹ́ meji (40,000) ọkunrin tí wọ́n ti múra ogun, ni wọ́n rékọjá níwájú OLUWA lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹriko. OLUWA gbé Joṣua ga ní ojú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ní ọjọ́ náà, wọ́n sì bẹ̀rù rẹ̀, bí wọ́n ti bẹ̀rù Mose ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. OLUWA wí fún Joṣua pé, “Pàṣẹ fún àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Ẹ̀rí pé kí wọ́n jáde kúrò ninu odò Jọdani.” Joṣua bá pàṣẹ fún àwọn alufaa náà pé kí wọ́n jáde ninu odò. Nígbà tí àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu OLUWA jáde kúrò ninu odò Jọdani, bí wọ́n ti ń gbé ẹsẹ̀ lé ilẹ̀ gbígbẹ, ni omi odò náà pada sí ààyè rẹ̀. Odò náà sì kún bo gbogbo bèbè rẹ̀, bí ó ti wà tẹ́lẹ̀. Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù kinni ni àwọn eniyan náà gun òkè odò Jọdani. Wọ́n pàgọ́ sí Giligali ní ìhà ìlà oòrùn Jẹriko. Joṣua bá to àwọn òkúta mejila tí wọ́n kó jáde láti inú odò Jọdani kalẹ̀ ní Giligali. Ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Nígbà tí àwọn ọmọ yín bá bèèrè lọ́wọ́ àwọn baba wọn ní ọjọ́ iwájú pé báwo ni ti àwọn òkúta wọnyi ti jẹ́ rí? Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ yín mọ̀ pé àwọn ọmọ Israẹli kọjá odò Jọdani yìí lórí ilẹ̀ gbígbẹ. Nítorí OLUWA Ọlọrun yín mú kí odò Jọdani gbẹ títí ẹ fi rékọjá sí òdìkejì rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti mú kí Òkun Pupa gbẹ, títí tí ẹ fi là á kọjá. Kí gbogbo aráyé lè mọ̀ pé, OLUWA lágbára, kí ẹ sì lè máa bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín títí lae.” Nígbà tí gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Amori, tí wọ́n wà ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani, ati gbogbo ọba àwọn ará ilẹ̀ Kenaani, tí wọ́n wà ní etí Òkun gbọ́ pé OLUWA mú kí odò Jọdani gbẹ nítorí àwọn ọmọ Israẹli, títí tí wọ́n fi rékọjá sí òdìkejì rẹ̀, àyà wọn já, ìdààmú sì bá wọn, nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Nígbà náà ni OLUWA wí fún Joṣua pé, “Fi akọ òkúta ṣe abẹ, kí o sì fi kọ ilà abẹ́ lẹẹkeji fún àwọn ọmọ Israẹli.” Joṣua bá fi akọ òkúta ṣe abẹ, ó fi kọ ilà abẹ́ fún gbogbo ọkunrin Israẹli ní Gibeati Haaraloti. Ìdí tí Joṣua fi kọ ilà abẹ́ fún wọn ni pé, gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n lè jagun, tí wọ́n jáde láti ilẹ̀ Ijipti, ti kú lójú ọ̀nà ninu aṣálẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti jáde láti ilẹ̀ Ijipti. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn tí wọ́n jáde láti ilẹ̀ Ijipti ni wọ́n kọ ilà abẹ́, ṣugbọn gbogbo àwọn tí wọ́n bí lójú ọ̀nà ninu aṣálẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n jáde ní ilẹ̀ Ijipti kò kọ ilà. Nítorí pé ogoji ọdún ni àwọn ọmọ Israẹli fi ń rìn kiri láàrin aṣálẹ̀, títí tí àwọn ọkunrin tí wọ́n lè jagun, tí wọ́n jáde láti Ijipti fi parun tán, nítorí wọn kò gbọ́ ti OLUWA wọn. OLUWA sì ti búra pé, òun kò ní jẹ́ kí wọ́n rí ilẹ̀ tí òun ti búra láti fún àwọn baba wọn, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin. Nítorí náà, àwọn ọmọ wọn tí OLUWA gbé dìde dípò wọn ni Joṣua kọ ilà abẹ́ fún, nítorí pé ẹnikẹ́ni kò kọ wọ́n ní ilà ní ojú ọ̀nà. Nígbà tí àwọn eniyan náà kọ ilà abẹ́ tán, olukuluku wà ní ààyè rẹ̀ ninu àgọ́ títí egbò wọn fi jinná. OLUWA wí fún Joṣua pé, “Lónìí yìí ni mo mú ẹ̀gàn àwọn ará Ijipti kúrò lára yín.” Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní Giligali títí di òní olónìí. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli pàgọ́ sí Giligali, wọ́n ṣe àjọ̀dún àjọ ìrékọjá ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrinla oṣù náà, ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹriko. Òwúrọ̀ ọjọ́ keji lẹ́yìn àjọ ìrékọjá ni ìgbà kinni tí wọ́n fi ẹnu kàn ninu èso ilẹ̀ náà, wọ́n jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà ati ọkà gbígbẹ. Mana kò dà ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, àwọn ọmọ Israẹli kò rí i kó mọ́, lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹ ninu èso ilẹ̀ náà. Ṣugbọn wọ́n jẹ ninu èso ilẹ̀ Kenaani ní gbogbo ọdún náà. Nígbà tí Joṣua súnmọ́ ìlú Jẹriko, ó gbé ojú sókè, ó sì rí i tí ọkunrin kan dúró níwájú rẹ̀ pẹlu idà lọ́wọ́. Joṣua lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó bi í pé, “Tiwa ni ò ń ṣe ni, tabi ti àwọn ọ̀tá wa?” Ọkunrin náà dáhùn pé, “Rárá, mo wá gẹ́gẹ́ bíi balogun àwọn ọmọ ogun OLUWA ni.” Joṣua bá dojúbolẹ̀, ó sin OLUWA, ó sì bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe, OLUWA mi?” Balogun àwọn ọmọ ogun OLUWA dá Joṣua lóhùn pé, “Bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ, nítorí ibi tí o dúró sí yìí, ilẹ̀ mímọ́ ni.” Joṣua sì bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀. Wọ́n ti ìlẹ̀kùn odi Jẹriko ninu ati lóde, nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Ẹnikẹ́ni kò lè jáde, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò lè wọlé. OLUWA sọ fún Joṣua pé, “Wò ó! Mo ti fi Jẹriko lé ọ lọ́wọ́ ati ọba wọn ati àwọn akikanju wọn. Ìwọ ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ yóo rìn yípo ìlú náà lẹ́ẹ̀kan lojumọ fún ọjọ́ mẹfa. Kí àwọn alufaa meje mú fèrè ogun kọ̀ọ̀kan tí wọ́n fi ìwo àgbò ṣe lọ́wọ́ níwájú Àpótí Majẹmu. Ní ọjọ́ keje ẹ óo yípo ìlú náà nígbà meje, àwọn alufaa yóo máa fọn fèrè ogun wọn. Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè ogun náà gidigidi, tí ẹ sì gbọ́ ìró rẹ̀, kí gbogbo àwọn eniyan hó yèè! Ògiri ìlú náà yóo sì wó. Kí olukuluku àwọn ọmọ ogun wọ inú ìlú náà lọ tààrà.” Joṣua, ọmọ Nuni, bá pe àwọn alufaa, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gbé Àpótí Majẹmu, kí meje ninu yín sì mú fèrè ogun tí wọ́n fi ìwo àgbò ṣe lọ́wọ́ níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA.” Ó sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ máa tẹ̀síwájú, ẹ rìn yípo ìlú náà kí àwọn ọmọ ogun ṣáájú Àpótí Majẹmu OLUWA.” Gẹ́gẹ́ bí Joṣua ti pàṣẹ fún àwọn eniyan náà, àwọn alufaa meje mú fèrè ogun tí wọ́n fi ìwo àgbò ṣe lọ́wọ́ níwájú OLUWA, wọ́n ṣáájú, wọ́n ń fọn fèrè ogun wọn; àwọn tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu OLUWA sì tẹ̀lé wọn. Àwọn kan ninu àwọn ọmọ ogun ṣáájú àwọn alufaa tí wọn ń fọn fèrè ogun, àwọn kan sì tẹ̀lé Àpótí Majẹmu. Àwọn tí wọn ń fọn fèrè ogun sì ń fọn ọ́n lemọ́lemọ́. Joṣua pàṣẹ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ pariwo, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ gbọ́ ohùn yín. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ rárá títí di ọjọ́ tí n óo sọ pé kí ẹ hó, nígbà náà ni ẹ óo tó hó.” Bẹ́ẹ̀ ni ó mú kí wọn gbé Àpótí Majẹmu OLUWA yí ìlú náà po lẹ́ẹ̀kan, nígbà tí ó di alẹ́, wọ́n pada sinu àgọ́ wọn, wọ́n sì sùn sibẹ. Joṣua dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, àwọn alufaa gbé Àpótí Majẹmu OLUWA. Àwọn alufaa meje tí wọ́n mú fèrè ogun tí wọ́n fi ìwo àgbò ṣe lọ́wọ́ níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA kọjá siwaju, wọ́n sì ń fọn fèrè ogun wọn lemọ́lemọ́. Àwọn kan ninu àwọn ọmọ ogun wà níwájú wọn, àwọn kan sì tẹ̀lé Àpótí Majẹmu OLUWA. Àwọn tí ń fọn fèrè ogun ń fọn ọ́n lemọ́lemọ́. Ní ọjọ́ keji, wọ́n yípo ìlú náà lẹ́ẹ̀kan, wọn sì pada sinu àgọ́ wọn. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe fún ọjọ́ mẹfa. Ní ọjọ́ keje, wọ́n gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu, wọ́n yípo ìlú náà bí wọ́n ti máa ń ṣe, nígbà meje. Ọjọ́ keje yìí nìkan ṣoṣo ni wọ́n yípo rẹ̀ lẹẹmeje. Nígbà tí ó di ẹẹkeje, lẹ́yìn tí àwọn alufaa fọn fèrè wọn, Joṣua pàṣẹ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ hó yèè! Nítorí OLUWA ti fi ìlú yìí le yín lọ́wọ́. OLUWA ti yà á sọ́tọ̀ fún ìparun, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀, àfi Rahabu, aṣẹ́wó, ati àwọn tí wọ́n wà ninu ilé pẹlu rẹ̀, ni yóo wà láàyè; nítorí òun ni ó gbé àwọn amí tí a rán pamọ́. Ẹ yẹra fún ohunkohun tí OLUWA ti yà sọ́tọ̀ fún ìparun, kí ẹ má baà di ẹni ègún nípa mímú ohun tí OLUWA ti yà sọ́tọ̀, kí ẹ má baà sọ àgọ́ Israẹli di ohun ìparun, kí ẹ sì kó ìyọnu bá a. Ṣugbọn gbogbo fadaka ati wúrà ati àwọn ohun èlò idẹ ati ti irin jẹ́ ohun ìyàsọ́tọ̀ fún OLUWA, inú ilé ìṣúra OLUWA ni a óo kó wọn sí.” Àwọn alufaa fọn fèrè ogun, bí àwọn eniyan ti gbọ́ ìró fèrè, gbogbo wọn hó yèè! Odi ìlú náà sì wó lulẹ̀. Gbogbo àwọn ọmọ ogun bá rọ́ wọ ààrin ìlú, wọ́n sì gba ìlú náà. Wọ́n run gbogbo àwọn ará ìlú náà patapata: atọkunrin, atobinrin, àtọmọdé, àtàgbà, àtakọ mààlúù, ataguntan, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́; gbogbo wọn ni wọ́n fi idà parun. Joṣua sọ fún àwọn ọkunrin meji tí wọ́n lọ ṣe amí ilẹ̀ náà pé, “Ẹ wọ ilé aṣẹ́wó náà lọ, kí ẹ sì mú obinrin náà wá ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti búra fún un.” Àwọn ọkunrin tí wọ́n lọ ṣe amí náà bá wọlé, wọ́n mú Rahabu jáde, ati baba rẹ̀, ati ìyá rẹ̀, ati àwọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo àwọn ìbátan rẹ̀, wọ́n sì kó wọn sí ẹ̀yìn àgọ́ àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n dáná sun ìlú náà ati gbogbo nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀, àfi fadaka ati wúrà, ati àwọn ohun èlò idẹ, ati ti irin, ni wọ́n kó lọ sinu ilé ìṣúra OLUWA. Ṣugbọn Joṣua dá Rahabu aṣẹ́wó sí, ati ilé baba rẹ̀, ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀, wọ́n sì ń gbé ààrin àwọn ọmọ Israẹli títí di òní yìí; nítorí pé, Rahabu ni ó gbé àwọn amí tí Joṣua rán lọ wo ìlú Jẹriko pamọ́. Joṣua bá gégùn-ún nígbà náà pé, “Ẹni ìfibú OLUWA ni ẹnikẹ́ni tí ó bá dìde láti tún ìlú Jẹriko kọ́. Àkọ́bí ẹni tí ó bá fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ yóo kú, àbíkẹ́yìn rẹ̀ yóo kú nígbà tí ó bá gbé ìlẹ̀kùn ibodè rẹ̀ ró.” OLUWA wà pẹlu Joṣua, òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo ilẹ̀ náà. Àwọn ọmọ Israẹli dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA nítorí pé ẹnìkan mú ninu àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀. Akani ọmọ Karimi, ọmọ Sabidi, ọmọ Sera, láti inú ẹ̀yà Juda, mú ninu àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀, inú sì bí OLUWA gidigidi sí àwọn ọmọ Israẹli. Joṣua rán àwọn ọkunrin kan láti Jẹriko lọ sí ìlú Ai, lẹ́bàá Betafeni ní ìhà ìlà oòrùn Bẹtẹli, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ṣe amí ilẹ̀ náà wá.” Àwọn ọkunrin náà lọ ṣe amí ìlú Ai. Wọ́n pada tọ Joṣua wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Má wulẹ̀ jẹ́ kí gbogbo àwọn eniyan lọ gbógun ti ìlú Ai, yan àwọn eniyan bí ẹgbaa (2,000) tabi ẹgbẹẹdogun (3,000) kí wọ́n lọ gbógun ti ìlú náà. Má wulẹ̀ lọ dààmú gbogbo àwọn eniyan lásán, nítorí pé àwọn ará Ai kò pọ̀ rárá.” Nítorí náà, nǹkan bí ẹgbẹẹdogun (3,000) ninu àwọn ọmọ Israẹli lọ gbógun tì wọ́n. Ṣugbọn wọ́n sá níwájú àwọn ará Ai. Àwọn ọmọ ogun Ai pa tó mẹrindinlogoji (36) ninu wọn, wọ́n sì lé gbogbo wọn kúrò ní ẹnubodè wọn títí dé Ṣebarimu. Wọ́n ń pa àwọn ọmọ Israẹli bí wọ́n ti ń dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè náà. Ọkàn àwọn ọmọ Israẹli bá dààmú, àyà wọn sì já. Joṣua fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ hàn, òun ati àwọn àgbààgbà Israẹli dojúbolẹ̀ níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA títí di ìrọ̀lẹ́, wọ́n sì ku eruku sórí. Joṣua bá gbadura, ó ní, “Yéè! OLUWA Ọlọrun! Kí ló dé tí o fi kó àwọn eniyan wọnyi gòkè odò Jọdani láti fà wọ́n lé àwọn ará Amori lọ́wọ́ láti pa wọ́n run? Ìbá tẹ́ wa lọ́rùn kí á wà ní òdìkejì odò Jọdani, kí á sì máa gbé ibẹ̀. OLUWA, kí ni mo tún lè sọ, nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ti sá níwájú àwọn ọ̀tá wọn? Àwọn ará Kenaani, ati gbogbo àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà yóo gbọ́, wọn yóo yí wa po, wọn yóo sì pa wá run kúrò lórí ilẹ̀ ayé, OLUWA! Kí lo wá fẹ́ ṣe, nítorí orúkọ ńlá rẹ?” Nígbà náà ni OLUWA wí fun Joṣua pé, “Dìde. Kí ló dé tí o fi dojúbolẹ̀? Israẹli ti ṣẹ̀, wọ́n ti rú òfin mi. Wọ́n ti mú ninu àwọn ohun tí a yà sọ́tọ̀, wọ́n ti jalè, wọ́n ti purọ́, wọn sì ti fi ohun tí wọ́n jí pamọ́ sábẹ́ àwọn ohun ìní wọn. Ìdí nìyí tí àwọn ọmọ Israẹli kò fi lè dúró níwájú àwọn ọ̀tá wọn. Wọ́n sá níwájú àwọn ọ̀tá wọn nítorí pé, wọ́n ti di ẹni ìparun. N kò ní wà pẹlu yín mọ́, àfi bí ẹ bá run àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ tí ó wà láàrin yín. Ẹ dìde, ẹ ya àwọn eniyan náà sí mímọ́; kí ẹ sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ ya ara yín sí mímọ́ fún ọ̀la, nítorí pé OLUWA Ọlọrun Israẹli ti sọ pé àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ wà láàrin ẹ̀yin ọmọ Israẹli. Ẹ kò sì ní lè dúró níwájú àwọn ọ̀tá yín títí tí ẹ óo fi kó àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ kúrò láàrin yín.’ Nítorí náà, nígbà tí ó bá di òwúrọ̀ ọ̀la, a óo mú gbogbo yín wá siwaju OLUWA ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan; ẹ̀yà tí OLUWA bá mú yóo wá ní agbo-ilé agbo-ilé. Agbo-ilé tí OLUWA bá mú yóo wá ní ìdílé-ìdílé. Àwọn ọkunrin tí ó wà ninu ìdílé tí OLUWA bá mú yóo wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. Ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá mú pẹlu àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ náà, iná ni a óo dá sun àtòun, ati gbogbo nǹkan tí ó ní, nítorí pé ó ti ṣẹ̀ sí majẹmu OLUWA. Ó ti ṣe ohun ìtìjú ní Israẹli.” Joṣua gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu, ó kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli wá ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, wọ́n bá mú ẹ̀yà Juda. Ó kó ẹ̀yà Juda wá ní agbo-ilé kọ̀ọ̀kan, wọn sì mú agbo-ilé Sera. Ó kó agbo-ilé Sera wá, wọ́n sì fa àwọn ọkunrin ibẹ̀ kalẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, wọ́n bá mú Sabidi. Wọ́n sì fa àwọn ọkunrin ìdílé Sabidi kalẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, wọ́n bá mú Akani ọmọ Karimi, ọmọ Sabidi, ọmọ Sera, ti ẹ̀yà Juda. Joṣua wí fún Akani pé, “Ọmọ mi, fi ògo fún OLUWA Ọlọrun Israẹli, kí o sì yìn ín. Jẹ́wọ́ ohun tí o ṣe, má fi pamọ́ fún mi.” Akani dá Joṣua lóhùn pé, “Lóòótọ́ ni mo ti ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun Israẹli. Ohun tí mo sì ṣe nìyí: Nígbà tí mo wo ààrin àwọn ìkógun, mo rí ẹ̀wù àwọ̀lékè dáradára kan láti Ṣinari, ati igba ìwọ̀n Ṣekeli fadaka, ati ọ̀pá wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọta Ṣekeli, wọ́n wọ̀ mí lójú, mo bá kó wọn, mo sì bò wọ́n mọ́lẹ̀ ninu àgọ́ mi. Fadaka ni mo fi tẹ́lẹ̀.” Joṣua bá ranṣẹ, wọ́n sáré lọ wo inú àgọ́ rẹ̀, wọ́n bá àwọn nǹkan náà ní ibi tí ó bò wọ́n mọ́, ó fi fadaka tẹ́lẹ̀. Wọ́n hú wọn jáde ninu àgọ́ rẹ̀, wọ́n kó wọn wá siwaju Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì tẹ́ wọn kalẹ̀ níwájú OLUWA. Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá mú Akani, ọmọ Sera, ati fadaka, ati ẹ̀wù àwọ̀lékè, ati ọ̀pá wúrà, ati àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin, àwọn akọ mààlúù rẹ̀ ati àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, àwọn aguntan rẹ̀ ati àgọ́ rẹ̀, ati ohun gbogbo tí ó ní, wọ́n kó wọn lọ sí àfonífojì Akori. Joṣua bá bi í pé, “Kí ló dé tí o fi kó wa sinu gbogbo ìyọnu yìí? OLUWA sì ti kó ìyọnu bá ìwọ náà lónìí.” Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá sọ wọ́n ní òkúta pa, wọ́n sì dáná sun wọ́n. Wọ́n kó òkítì òkúta jọ sórí rẹ̀. Òkítì òkúta náà sì wà níbẹ̀ títí di òní olónìí. OLUWA bá yí ibinu rẹ̀ pada. Nítorí náà ni wọ́n ṣe ń pe ibẹ̀ ní àfonífojì Akori. OLUWA sọ fún Joṣua pé, “Má bẹ̀rù, má sì ṣe jẹ́ kí àyà fò ọ́, kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ kí o lọ sí ìlú Ai. Wò ó! Mo ti fi ọba Ai, ati àwọn eniyan rẹ̀, ìlú rẹ̀ ati ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́. Bí o ti ṣe sí Jẹriko ati ọba rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí o ṣe sí Ai ati ọba rẹ̀. Ṣugbọn ẹ dá ìkógun ati àwọn ẹran ọ̀sìn tí ó wà níbẹ̀ sí, kí ẹ sì kó o gẹ́gẹ́ bí ìkógun fún ara yín; ẹ ba ní ibùba lẹ́yìn odi ìlú náà.” Joṣua bá múra, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n lọ sí ìlú Ai. Joṣua yan ẹgbaa mẹẹdogun (30,000) akikanju ọmọ ogun, ó rán wọn jáde ní alẹ́. Ó pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ lọ fara pamọ́ lẹ́yìn ìlú náà, ẹ má jìnnà sí i pupọ, ṣugbọn ẹ wà ní ìmúrasílẹ̀. Èmi ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu mi nìkan ni a óo wọ ìlú náà. Nígbà tí wọ́n bá jáde sí wa láti bá wa jà bí i ti àkọ́kọ́, a óo sá fún wọn. Wọn yóo máa lé wa lọ títí tí a óo fi tàn wọ́n jáde kúrò ninu ìlú, nítorí wọn yóo ṣe bí à ń sálọ fún wọn bíi ti àkọ́kọ́ ni; nítorí náà ni a óo ṣe sá fún wọn. Ẹ̀yin ẹ dìde níbi tí ẹ farapamọ́ sí, kí ẹ sì gba ìlú náà, nítorí OLUWA Ọlọrun yóo fi lé yín lọ́wọ́. Gbàrà tí ẹ bá ti gba ìlú náà tán, ẹ ti iná bọ̀ ọ́, kí ẹ sì ṣe bí àṣẹ OLUWA. Ó jẹ́ àṣẹ tí mo pa fun yín.” Joṣua bá rán wọn ṣiwaju, wọ́n sì lọ sí ibi tí wọn yóo fara pamọ́ sí ní ìwọ̀ oòrùn Ai, láàrin Ai ati Bẹtẹli. Ṣugbọn Joṣua wà pẹlu àwọn eniyan ní gbogbo òru ọjọ́ náà. Joṣua dìde ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, ó pe gbogbo àwọn eniyan náà jọ. Òun ati àwọn àgbààgbà Israẹli ṣáájú wọn, wọ́n lọ sí Ai. Gbogbo àwọn ọmọ ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá a lọ títí wọ́n fi fẹ́rẹ̀ dé ìlú Ai, wọ́n sì pàgọ́ wọn sí apá ìhà àríwá ìlú náà, odò kan ni ó wà láàrin wọn ati ìlú Ai. Joṣua ṣa nǹkan bí ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) ọmọ ogun, ó fi wọ́n pamọ́ sí ààrin Bẹtẹli ati Ai ní apá ìwọ̀ oòrùn Ai. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe fi àwọn ọmọ ogun wọn sí ipò, àwọn tí wọn yóo gbógun ti ìlú gan-an wà ní apá ìhà àríwá ìlú, àwọn tí wọn yóo wà lẹ́yìn wà ní apá ìwọ̀ oòrùn, ṣugbọn Joṣua alára wà ní àfonífojì ní gbogbo òru ọjọ́ náà. Nígbà tí ọba Ai ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ rí i, gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ní ìlú náà bá yára, wọ́n jáde lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ apá ọ̀nà Araba láti kó ogun pàdé àwọn ọmọ Israẹli, ṣugbọn wọn kò mọ̀ pé àwọn kan ti farapamọ́ sẹ́yìn ìlú. Joṣua ati gbogbo ọmọ Israẹli tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá ṣe bí ẹni pé àwọn ará Ai ti ṣẹgun àwọn, wọ́n sì sá gba ọ̀nà aṣálẹ̀ lọ. Àwọn ará Ai bá pe gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ní ìlú jọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn ọmọ Israẹli lọ. Bí wọ́n ti ń lé Joṣua lọ ni wọ́n ń jìnnà sí ìlú. Kò sì sí ẹyọ ọkunrin kan tí ó kù ní Ai ati Bẹtẹli tí kò jáde láti lépa àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n fi ìlẹ̀kùn ẹnubodè sílẹ̀ ní ṣíṣí, wọ́n ń lé àwọn ọmọ Israẹli lọ. OLUWA sọ fun Joṣua pé, “Na ọ̀kọ̀ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ sí ọ̀kánkán Ai, nítorí n óo fi lé ọ lọ́wọ́.” Joṣua bá na ọ̀kọ̀ ọwọ́ rẹ̀ sí ọ̀kánkán ìlú náà. Gbogbo àwọn tí wọn farapamọ́ bá yára dìde ní ibi tí wọ́n wà. Bí Joṣua ti na ọwọ́ rẹ̀, wọ́n sáré wọ inú ìlú náà, wọ́n gbà á, wọ́n sì yára sọ iná sí i. Nígbà tí àwọn ará Ai bojú wẹ̀yìn, tí wọ́n rí i tí èéfín yọ ní ìlú wọn, wọn kò ní agbára mọ́ láti sá síhìn-ín tabi sọ́hùn-ún, nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n sá gba ọ̀nà aṣálẹ̀ lọ yíjú pada sí wọn. Nígbà tí Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli rí i pé àwọn tí wọn farapamọ́ ti gba ìlú náà, tí èéfín sì ti yọ sókè, wọ́n yipada, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pa àwọn ará Ai. Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ninu ìlú náà jáde sí wọn, àwọn ará Ai sì wà ní agbede meji àwọn ọmọ Israẹli, àwọn kan wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni, àwọn kan wà ní ẹ̀gbẹ́ keji. Àwọn ọmọ Israẹli bá bẹ̀rẹ̀ sí í pa wọ́n ní ìpakúpa títí tí kò fi ku ẹyọ ẹnìkan. Ṣugbọn wọ́n mú ọba Ai láàyè, wọ́n sì mú un tọ Joṣua wá. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ti fi idà pa gbogbo àwọn ará Ai tán ninu aṣálẹ̀, ní ibi tí wọ́n ti ń lé wọn lọ, wọ́n pada sí ìlú Ai, wọ́n sì fi idà pa gbogbo wọn patapata. Gbogbo àwọn ará Ai tí wọ́n pa ní ọjọ́ náà, ati ọkunrin, ati obinrin, gbogbo wọn jẹ́ ẹgbaafa (12,000). Nítorí pé ọwọ́ tí Joṣua fi na ọ̀kọ̀ sókè, kò gbé e sílẹ̀ títí tí wọ́n fi pa gbogbo àwọn ará Ai tán. Àfi ẹran ọ̀sìn ati dúkìá ìlú náà ni àwọn ọmọ Israẹli kó ní ìkógun gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Joṣua. Joṣua dáná sun ìlú Ai, ó sì sọ ọ́ di òkítì àlàpà títí di òní olónìí. Ó so ọba Ai kọ́ sórí igi kan títí di ìrọ̀lẹ́, nígbà tí oòrùn ń lọ wọ̀, Joṣua pàṣẹ pé kí wọn já òkú rẹ̀ lulẹ̀, wọ́n sì wọ́ ọ sí ẹnu ọ̀nà bodè ìlú náà, wọ́n kó òkúta jọ lé e lórí, òkúta náà wà níbẹ̀ títí di òní olónìí. Joṣua tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA Ọlọrun Israẹli ní orí òkè Ebali, bí Mose iranṣẹ OLUWA ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli ati gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ ọ́ sí inú ìwé òfin Mose pé, “Pẹpẹ tí wọ́n fi òkúta tí wọn kò gbẹ́ kọ́, tí ẹnikẹ́ni kò gbé ohun èlò irin sókè láti gbẹ́ òkúta rẹ̀.” Wọ́n rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia sí OLUWA lórí rẹ̀. Joṣua mú òfin tí Mose kọ tẹ́lẹ̀, ó dà á kọ sórí àwọn òkúta náà lójú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli. Gbogbo Israẹli, ati onílé, ati àlejò, gbogbo àwọn àgbààgbà, ati àwọn olórí, ati àwọn aṣiwaju dúró ní òdìkejì Àpótí Majẹmu OLUWA, níwájú àwọn alufaa, ọmọ Lefi, tí wọ́n ru Àpótí Majẹmu náà. Ìdajì wọn dúró níwájú òkè Ebali bí Mose, iranṣẹ OLUWA, ti pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n ṣe máa súre fún àwọn ọmọ Israẹli. Lẹ́yìn náà Joṣua ka gbogbo òfin náà sókè ati ibukun tí ó wà ninu rẹ̀, ati ègún, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin. Kò sí ohun tí Mose pa láṣẹ tí Joṣua kò kà sí etígbọ̀ọ́ gbogbo ìjọ ọmọ Israẹli, ati ọkunrin ati obinrin, ati ọmọde ati àlejò tí wọ́n wà ní ààrin wọn. Nígbà tí gbogbo àwọn ọba tí wọ́n wà ní agbègbè olókè, ní òdìkejì odò Jọdani ati àwọn tí wọ́n wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní etí òkun Mẹditarenia ní agbègbè Lẹbanoni, àwọn ará Hiti, àwọn ará Amori, àwọn ará Kenaani, àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi, ati àwọn ará Jebusi, gbọ́ nípa ìṣẹ́gun àwọn ọmọ Israẹli, gbogbo wọn parapọ̀, wọ́n fi ohùn ṣọ̀kan láti bá Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli jagun. Ṣugbọn nígbà tí àwọn ará Gibeoni gbọ́ ohun tí Joṣua ṣe sí ìlú Jẹriko ati Ai, wọ́n lo ọgbọ́n, wọ́n tọ́jú oúnjẹ, wọ́n mú àwọn àpò ìdọ̀họ tí wọ́n ti gbó, wọ́n dì wọ́n lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn. Wọ́n mú awọ ìpọnmi tí ó ti gbó, tí wọ́n sì ti lẹ̀, wọ́n wọ sálúbàtà tí ó ti gbó ati aṣọ àkísà, gbogbo oúnjẹ tí wọn mú lọ́wọ́ ni ó ti gbẹ, tí ó sì ti bu. Wọ́n tọ Joṣua lọ ninu àgọ́ tí ó wà ní Giligali, wọ́n wí fún òun ati àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ọ̀nà jíjìn ni a ti wá, nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á dá majẹmu.” Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli wí fún àwọn ará Hifi náà pé, “Bóyá nítòsí ibí ni ẹ ti wá, báwo ni a ṣe lè ba yín dá majẹmu?” Wọ́n sọ fún Joṣua pé “Iranṣẹ yín ni wá.” Joṣua bá dá wọn lóhùn pé, “Ta ni yín, níbo ni ẹ sì ti wá?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Láti ọ̀nà jíjìn ni àwa iranṣẹ rẹ ti wá nítorí orúkọ OLUWA Ọlọrun yín, nítorí a ti gbúròó rẹ̀ ati gbogbo ohun tí ó ṣe sí wọn ní ilẹ̀ Ijipti, ati gbogbo ohun tí ó ṣe sí àwọn ọba Amori mejeeji tí wọ́n wà ní òdìkejì odò Jọdani, Sihoni ọba àwọn ará Heṣiboni ati Ogu ọba àwọn ará Baṣani tí ń gbé Aṣitarotu.” Gbogbo àwọn àgbààgbà wa ati gbogbo àwọn ará ilẹ̀ wa bá wí fún wa pé, “Ẹ wá lọ bá àwọn eniyan wọnyi, ẹ sì mú oúnjẹ lọ́wọ́ fún ìrìn àjò náà, ẹ wí fún wọn pé iranṣẹ yín ni wá, ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí á jọ dá majẹmu. Ẹ wò ó! Burẹdi wa nìyí, ó gbóná nígbà tí a dì í nílé fún ìrìn àjò yìí ní ọjọ́ tí a bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò náà. Ṣugbọn nisinsinyii, ó ti gbẹ, ó sì ti bu. Titun ni àwọn awọ ìpọnmi wọnyi nígbà tí a kó wọn jáde tí a sì pọn omi sinu wọn. Ẹ wò ó, wọ́n ti gbó, wọ́n sì ti ya. Àwọn aṣọ wa ati àwọn bàtà wa ti gbó nítorí ìrìn àjò náà jìn.” Àwọn ọmọ Israẹli bá wọn jẹ ninu oúnjẹ wọn, wọn kò sì bèèrè ìtọ́sọ́nà lọ́dọ̀ OLUWA. Joṣua bá wọn dá majẹmu alaafia, pé, àwọn kò ní pa wọ́n, àwọn àgbààgbà Israẹli sì búra fún wọn. Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹta tí wọ́n ti bá àwọn eniyan náà ṣe àdéhùn, ni wọ́n gbọ́ pé nítòsí wọn ni wọ́n wà, ati pé aládùúgbò ni wọ́n. Àwọn ọmọ Israẹli bá gbéra ní ọjọ́ kẹta, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ka àwọn ìlú wọn. Àwọn ìlú náà ni: Gibeoni, Kefira, Beeroti ati Kiriati Jearimu. Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli kò pa wọ́n, nítorí pé àwọn àgbààgbà wọn ti búra fún wọn ní orúkọ OLUWA Ọlọrun Israẹli. Gbogbo ìjọ eniyan bá bẹ̀rẹ̀ sí i kùn sí àwọn àgbààgbà. Ṣugbọn gbogbo àwọn àgbààgbà dá ìjọ eniyan náà lóhùn pé, “A ti búra fún wọn ní orúkọ OLUWA Ọlọrun Israẹli, a kò sì gbọdọ̀ fọwọ́ kàn wọ́n mọ́. Ohun tí a lè ṣe ni pé kí á dá wọn sí, kí ibinu OLUWA má baà wá sórí wa, nítorí ìbúra tí a ti ṣe fún wọn.” Àwọn àgbààgbà bá wí fún wọn pé, “Ẹ má pa wọ́n.” Àwọn àgbààgbà Israẹli bá pàṣẹ pé kí àwọn eniyan náà di aṣẹ́gi ati apọnmi fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli. Joṣua pè wọ́n, ó ní, “Kí ló dé tí ẹ fi tàn wá jẹ, tí ẹ wí fún wa pé, ọ̀nà jíjìn ni ẹ ti wá, nígbà tí ó jẹ́ pé ààrin wa níbí ni ẹ̀ ń gbé? Nítorí náà, ẹ di ẹni ìfibú; ẹrú ni ẹ óo máa ṣe, ẹ̀yin ni ẹ óo máa ṣẹ́ igi tí ẹ óo sì máa pọnmi fun ilé Ọlọrun mi.” Wọ́n dá Joṣua lóhùn pé, “Wọ́n sọ fún àwa iranṣẹ yín pé, dájúdájú, OLUWA Ọlọrun yín ti pàṣẹ fún Mose láti fun yín ní gbogbo ilẹ̀ yìí, ati láti pa gbogbo àwọn eniyan ibẹ̀; nítorí náà ni ẹ̀rù yín ṣe bà wá. Kí ẹ má baà pa wá run ni a fi ṣe ohun tí a ṣe. Sibẹsibẹ, ọwọ́ yín náà ni a ṣì wà; ẹ ṣe wá bí ó bá ti tọ́ lójú yín.” Ohun tí Joṣua ṣe fún wọn ni pé ó gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọmọ Israẹli, kò jẹ́ kí wọ́n pa wọ́n. Ṣugbọn láti ọjọ́ náà ni Joṣua ti sọ wọ́n di ẹni tí ó ń ṣẹ́ igi, tí ó sì ń pọn omi fún àwọn eniyan Israẹli, ati fún pẹpẹ OLUWA. Títí di òní, àwọn ni wọ́n ń ṣe iṣẹ́ náà ní ibi tí OLUWA yàn pé kí àwọn ọmọ Israẹli ti máa jọ́sìn. Nígbà tí Adonisedeki, ọba Jerusalẹmu, gbọ́ bí Joṣua ṣe gba ìlú Ai, ati pé ó pa ìlú Ai ati ọba rẹ̀ run, bí ó ti ṣe sí ìlú Jẹriko ati ọba rẹ̀; ati pé àwọn ará Gibeoni ti bá àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu alaafia, wọ́n sì ń gbé ààrin wọn, ẹ̀rù bà á gidigidi, nítorí pé ìlú ńlá ni ìlú Gibeoni bí ọ̀kan ninu àwọn ìlú ọba aládé. Gibeoni tóbi ju ìlú Ai lọ, akọni sì ni gbogbo àwọn ọkunrin ibẹ̀. Nítorí náà, Adonisedeki ọba Jerusalẹmu ranṣẹ sí Hohamu ọba Heburoni, Piramu ọba Jarimutu, Jafia ọba Lakiṣi ati Debiri ọba Egiloni, pé, “Ẹ wá ràn mí lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ kí á kọlu Gibeoni, nítorí pé ó ti bá Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu alaafia.” Nígbà náà ni àwọn ọba Amori maraarun, ọba Jerusalẹmu, ti Heburoni, ti Jarimutu, ti Lakiṣi, ati ti Egiloni parapọ̀, wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn jọ. Wọ́n lọ dó ti Gibeoni, wọ́n sì ń bá a jagun. Àwọn ará Gibeoni bá ranṣẹ sí Joṣua ní àgọ́ tí ó wà ní Giligali. Wọ́n ní, “Ẹ má fi àwa iranṣẹ yín sílẹ̀! Ẹ tètè yára wá gbà wá kalẹ̀, ẹ wá ràn wá lọ́wọ́. Nítorí pé, gbogbo àwọn ọba Amori, tí wọn ń gbé agbègbè olókè, ti kó ara wọn jọ sí wa.” Joṣua bá lọ láti Giligali, òun ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀, pẹlu gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ akikanju ati akọni. OLUWA wí fún Joṣua pé, “Má bẹ̀rù wọn, nítorí pé mo ti fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́. Ẹnikẹ́ni ninu wọn kò ní lè ṣẹgun rẹ.” Joṣua jálù wọ́n lójijì, lẹ́yìn tí ó ti fi gbogbo òru rìn láti Giligali. OLUWA mú kí ìpayà bá àwọn ará Amori, nígbà tí wọ́n rí àwọn ọmọ Israẹli, àwọn ọmọ Israẹli bá bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n ní ìpakúpa ní Gibeoni. Wọ́n lé wọn gba ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Beti Horoni, wọ́n sì pa wọ́n títí dé Aseka ati Makeda. Bí wọ́n sì ti ń sá lọ fún àwọn ọmọ Israẹli, tí wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ ní ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Beti Horoni, OLUWA mú kí àwọn òkúta ńláńlá máa bọ́ lù wọ́n láti ojú ọ̀run, títí tí wọ́n fi dé Aseka, wọ́n sì kú. Àwọn tí òkúta ńláńlá wọnyi pa pọ̀ ju àwọn tí àwọn ọmọ Israẹli fi idà pa lọ. Ní ọjọ́ tí OLUWA fi àwọn ará Amori lé àwọn ọmọ Israẹli lọ́wọ́, Joṣua bá OLUWA sọ̀rọ̀ lójú gbogbo Israẹli, ó ní, “Ìwọ oòrùn, dúró jẹ́ẹ́ ní Gibeoni. Ìwọ òṣùpá, sì dúró jẹ́ẹ́ ní àfonífojì Aijaloni.” Oòrùn bá dúró jẹ́ẹ́, òṣùpá náà sì dúró jẹ́ẹ́, títí tí àwọn ọmọ Israẹli fi gbẹ̀san tán lára àwọn ọ̀tá wọn. Wọ́n kọ ọ́ sinu ìwé Jaṣari pé, oòrùn dúró ní agbede meji ojú ọ̀run, kò sì tètè wọ̀ fún bí odidi ọjọ́ kan. Irú ọjọ́ bẹ́ẹ̀ kò wáyé rí ṣáájú ìgbà náà, bẹ́ẹ̀ sì ni, láti ìgbà náà, kò sì tíì tún ṣẹlẹ̀, pé kí OLUWA gba ọ̀rọ̀ sí eniyan lẹ́nu, èyí ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ nítorí pé, OLUWA jà fún Israẹli. Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli bá pada sí àgọ́ wọn ní Giligali. Àwọn ọba maraarun sá, wọ́n sì fi ara pamọ́ sinu ihò tí ó wà ní Makeda. Àwọn kan wá sọ fún Joṣua pé wọ́n ti rí àwọn ọba maraarun ní ibi tí wọ́n fi ara pamọ́ sí ní Makeda. Joṣua dá wọn lóhùn pé, “Ẹ yí òkúta ńláńlá dí ẹnu ihò náà kí ẹ sì fi àwọn eniyan sibẹ, láti máa ṣọ́ wọn. Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ dúró níbẹ̀, ẹ máa lé àwọn ọ̀tá yín lọ, kí ẹ máa pa wọ́n láti ẹ̀yìn. Ẹ má jẹ́ kí wọ́n pada wọnú ìlú wọn, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín ti fi wọ́n le yín lọ́wọ́.” Nígbà tí Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli ti pa wọ́n ní ìpakúpa tán, tí wọ́n sì fẹ́rẹ̀ pa gbogbo wọn run, tí àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù sì ti sá wọ àwọn ìlú olódi wọn lọ tán, gbogbo àwọn eniyan pada sọ́dọ̀ Joṣua ní àgọ́ tí ó wà ní Makeda láìsí ewu. Kò sì sí ẹni tí ó sọ ìsọkúsọ sí àwọn ọmọ Israẹli. Lẹ́yìn náà, Joṣua ní, “Ẹ ṣí ẹnu ihò náà, kí ẹ sì kó àwọn ọba maraarun náà wá fún mi.” Wọ́n bá kó wọn jáde, láti inú ihò: ọba Jerusalẹmu, ọba Heburoni, ọba Jarimutu, ọba Lakiṣi, ati ọba Egiloni. Nígbà tí wọ́n kó àwọn ọba náà dé ọ̀dọ̀ Joṣua, ó pe gbogbo àwọn ọkunrin Israẹli jọ, ó sọ fún àwọn ọ̀gágun tí wọ́n bá a lọ sí ojú ogun pé, “Ẹ súnmọ́ mi, kí ẹ sì fi ẹsẹ̀ yín tẹ ọrùn àwọn ọba wọnyi.” Wọ́n bá súnmọ́ Joṣua, wọ́n sì tẹ àwọn ọba náà lọ́rùn mọ́lẹ̀. Joṣua bá sọ fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí àyà yín já. Ẹ múra, kí ẹ sì ṣe ọkàn gírí, nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni OLUWA yóo ṣe sí gbogbo àwọn ọ̀tá yín, tí ẹ̀ ń bá jà.” Lẹ́yìn náà, Joṣua fi idà pa wọ́n, ó so wọ́n kọ́ orí igi marun-un, wọ́n sì wà lórí àwọn igi náà títí di ìrọ̀lẹ́. Nígbà tí oòrùn ń lọ wọ̀, Joṣua pàṣẹ pé kí wọ́n já òkú wọn lulẹ̀ kí wọ́n sì sọ wọ́n sinu ihò tí wọ́n sápamọ́ sí, wọ́n sì yí òkúta ńlá dí ẹnu ihò náà. Ó wà níbẹ̀ títí di òní olónìí. Ní ọjọ́ náà gan-an ni Joṣua gba ìlú Makeda, ó sì fi idà pa àwọn eniyan inú rẹ̀ ati ọba wọn. Gbogbo àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ ni ó parun, kò dá ẹnikẹ́ni sí. Bí ó ti ṣe sí ọba Jẹriko náà ló ṣe sí ọba Makeda. Joṣua gbéra ní Makeda, ó kọjá lọ sí Libina pẹlu gbogbo Israẹli láti gbógun ti Libina. OLUWA sì fi ìlú Libina ati ọba rẹ̀ lé Israẹli lọ́wọ́. Wọ́n fi idà pa wọ́n, wọn kò ṣẹ́ ẹnikẹ́ni kù ninu wọn. Bí ó ti ṣe ọba Jẹriko, náà ló ṣe sí ọba ìlú náà. Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá gbéra láti Libina lọ sí Lakiṣi. Wọ́n dó tì í, wọ́n sì bá a jagun. OLUWA fi ìlú Lakiṣi lé àwọn ọmọ Israẹli lọ́wọ́, wọ́n sì gbà á ní ọjọ́ keji. Wọ́n fi idà pa gbogbo wọn patapata bí wọ́n ti ṣe pa àwọn ará Libina. Horamu ọba Geseri wá láti ran àwọn ará ìlú Lakiṣi lọ́wọ́, Joṣua gbógun tì í, ó sì pa òun ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ láìku ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo. Joṣua kúrò ní Lakiṣi, ó lọ sí Egiloni pẹlu gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n dó ti Egiloni, wọ́n sì bá a jagun. Wọ́n gba ìlú náà ní ọjọ́ náà, wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn eniyan ibẹ̀ patapata gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe sí àwọn ará Lakiṣi. Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Egiloni lọ sí Heburoni, wọ́n sì gbógun tì í. Wọ́n gba ìlú Heburoni, wọ́n sì fi idà pa ọba ìlú náà ati gbogbo àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀ láìku ẹnìkan, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe sí ìlú Egiloni tí wọn parun láìku ẹnìkan. Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá pada sí Debiri, wọ́n sì gbógun tì í. Wọ́n gba ìlú náà, wọ́n mú ọba ibẹ̀. Wọ́n gba àwọn ìlú kéékèèké agbègbè rẹ̀ pẹlu. Wọ́n fi idà pa ọba wọn ati gbogbo àwọn ará ìlú náà. Gbogbo wọn ni wọ́n pa láìku ẹnìkan. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe sí Heburoni, ati Libina ati ọba rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ṣe sí Debiri ati ọba rẹ̀. Joṣua ṣẹgun gbogbo ilẹ̀ náà, ati àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè, ati àwọn tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Nẹgẹbu ní apá gúsù, ati àwọn tí wọ́n wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, ati àwọn tí wọ́n wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè, ati gbogbo àwọn ọba wọn. Kò dá ẹnikẹ́ni sí, gbogbo wọn patapata ni ó parun gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA Ọlọrun Israẹli pa fún un. Joṣua ṣẹgun gbogbo wọn láti Kadeṣi Banea títí dé Gasa ati gbogbo agbègbè Goṣeni títí dé Gibeoni. Joṣua mú gbogbo àwọn ọba wọnyi, ó sì gba gbogbo ilẹ̀ wọn lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, nítorí pé OLUWA Ọlọrun jà fún Israẹli. Lẹ́yìn náà, Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pada sí àgọ́ wọn, ní Giligali. Nígbà tí Jabini ọba Hasori, gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó ranṣẹ sí Jobabu, ọba Madoni, ati sí ọba Ṣimironi, ati sí ọba Akiṣafu, ati sí àwọn ọba tí wọ́n wà ní àwọn ìlú olókè ti apá ìhà àríwá, ati sí àwọn tí wọ́n wà ní Araba ní ìhà gúsù Kineroti, ati sí àwọn tí wọ́n wà ní ẹsẹ̀ òkè, ati sí àwọn tí wọ́n wà ní Nafoti-dori ní apá ìwọ̀ oòrùn. Ó ranṣẹ sí àwọn ará Kenaani ní ìhà ìlà oòrùn, ati ti ìwọ̀ oòrùn, ati àwọn ará Amori, ati àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Perisi, ati àwọn ará Jebusi ní àwọn agbègbè olókè, ati àwọn ará Hifi tí wọ́n wà ní abẹ́ òkè Herimoni ní ilẹ̀ Misipa. Gbogbo wọn jáde pẹlu gbogbo ọmọ ogun wọn, wọ́n pọ̀ yanturu bí eṣú. Wọ́n dàbí iyanrìn etí òkun. Ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò lóǹkà. Gbogbo àwọn ọba wọnyi parapọ̀, wọ́n kó gbogbo ọmọ ogun wọn jọ láti bá Israẹli jagun. Wọ́n sì pàgọ́ sí etí odò Meromu. OLUWA sọ fún Joṣua pé, “Má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí pé ní ìwòyí ọ̀la, òkú wọn ni n óo fi lé Israẹli lọ́wọ́. Dídá ni kí ẹ dá àwọn ẹṣin wọn lẹ́sẹ̀, kí ẹ sì sun gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun wọn.” Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ bá jálù wọ́n lójijì ní etí odò Meromu, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn jagun. OLUWA fi wọ́n lé Israẹli lọ́wọ́, àwọn ọmọ ogun Israẹli sì bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n. Wọ́n lé wọn títí dé Sidoni ati Misirefoti Maimu, ati apá ìlà oòrùn títí dé àfonífojì Misipa, wọ́n pa wọ́n títí tí kò fi ku ẹyọ ẹnìkan. Joṣua ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ pé kí ó ṣe sí wọn: ó dá àwọn ẹṣin wọn lẹ́sẹ̀, ó sì sun àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn níná. Joṣua bá yipada, ó gba ìlú Hasori, ó sì fi idà pa ọba wọn, nítorí pé Hasori ni olú-ìlú ìjọba ilẹ̀ náà tẹ́lẹ̀ rí. Wọ́n fi idà pa gbogbo àwọn ará ìlú náà láìku ẹyọ ẹnìkan, wọ́n sì sun ìlú Hasori níná. Joṣua gba gbogbo ìlú àwọn ọba náà, ó kó àwọn ọba wọn, ó fi idà pa wọ́n, gẹ́gẹ́ bí Mose iranṣẹ OLUWA ti pàṣẹ fún un. Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli kò sun èyíkéyìí ninu àwọn ìlú tí wọ́n kọ́ sórí òkítì níná, àfi Hasori nìkan ni Joṣua dáná sun. Àwọn ọmọ Israẹli kó gbogbo dúkìá ìlú náà ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ní ìkógun, ṣugbọn wọ́n fi idà pa gbogbo àwọn eniyan ibẹ̀ run patapata, wọn kò dá ẹyọ ẹnìkan sí. Gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose, iranṣẹ rẹ̀, ni Mose náà ṣe pàṣẹ fún Joṣua, tí Joṣua sì ṣe bẹ́ẹ̀. Kò fi ohunkohun sílẹ̀ láìṣe, ninu gbogbo nǹkan tí OLUWA pa láṣẹ fún Mose. Gbogbo ilẹ̀ náà ni Joṣua gbà: ó gba àwọn agbègbè olókè, àwọn tí wọ́n wà ní Nẹgẹbu, gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní ilẹ̀ Goṣeni, àwọn ìlú tí ó wà ní ẹsẹ̀ òkè, àwọn tí ó wà ní Araba, ati gbogbo àwọn ìlú tí ó wà lórí àwọn òkè Israẹli ati ẹsẹ̀ òkè rẹ̀. Láti òkè Halaki títí lọ sí Seiri, títí dé Baaligadi ní àfonífojì Lẹbanoni ní ìsàlẹ̀ òkè Herimoni. Ó mú gbogbo àwọn ọba wọn, ó pa wọ́n. Joṣua bá àwọn ọba wọnyi jagun fún ìgbà pípẹ́. Kò sí ìlú tí ó bá àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu alaafia àfi àwọn ará Hifi tí wọn ń gbé ìlú Gibeoni. Gbogbo àwọn yòókù patapata ni wọ́n kó lójú ogun. Nítorí pé, OLUWA fúnra rẹ̀ ni ó mú kí ọkàn wọn le, kí wọ́n sì gbógun ti Israẹli, kí àwọn ọmọ Israẹli lè pa wọ́n run, kí wọ́n má baà ṣàánú wọn, ṣugbọn kí wọ́n pa wọ́n run gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. Ní àkókò yìí ni Joṣua pa ìran àwọn Anakimu run patapata ní gbogbo àwọn ìlú tí ó wà lórí òkè, àwọn ìlú bíi: Heburoni, Debiri, Anabu, ati àwọn ìlú tí wọ́n wà lórí òkè Juda, ati àwọn ìlú tí wọ́n wà lórí òkè Israẹli, gbogbo wọn patapata ni Joṣua parun, ati gbogbo ìlú wọn. Àwọn ìran Anakimu yìí kò kù sí ibikíbi ninu ilẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli, àfi ní ìlú Gasa, ìlú Gati, ati ìlú Aṣidodu ni àwọn díẹ̀ kù sí. Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ṣe gba gbogbo ilẹ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ fún Mose, ó sì pín in fún àwọn ọmọ Israẹli; ní ẹlẹ́yà-mẹ̀yà. Lẹ́yìn náà, wọ́n sinmi ogun jíjà. Àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun àwọn ọba wọnyi, wọ́n sì gba gbogbo ilẹ̀ wọn tí ó wà ní apá ìlà oòrùn, ní òdìkejì odò Jọdani, láti àfonífojì Arinoni títí dé òkè Herimoni, pẹlu gbogbo agbègbè Araba ní apá ìlà oòrùn. Wọ́n ṣẹgun Sihoni, ọba àwọn ará Amori, tí ń gbé ìlú Heṣiboni. Ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti Aroeri, tí ó wà ní etí àfonífojì Arinoni, ati láti agbede meji àfonífojì náà, títí dé odò Jaboku, tí í ṣe ààlà ilẹ̀ àwọn ará Amoni, ó jẹ́ ìdajì ilẹ̀ Gileadi; ati Araba, títí dé òkun Ṣinerotu ní apá ìlà oòrùn, ní ọ̀nà ìlú Beti Jeṣimotu, títí dé òkun Araba, (tí wọ́n tún ń pè ní Òkun Iyọ̀), títí lọ sí apá ìhà gúsù, títí dé ẹsẹ̀ òkè Pisiga. Wọ́n ṣẹgun Ogu, ọba Baṣani náà. Ogu yìí jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn tí ó kù ninu ìran Refaimu tí ń gbé Aṣitarotu ati Edirei. Lára ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ ni òkè Herimoni wà, ati ìlú Saleka, ati gbogbo Baṣani, títí dé ààlà ilẹ̀ àwọn ará Geṣuri, ati ti àwọn ará Maakati ati ìdajì Gileadi títí dé ààlà ọba Sihoni ti ìlú Heṣiboni. Mose, iranṣẹ OLUWA ati àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun àwọn ọba mejeeji yìí, ó sì pín ilẹ̀ wọn fún ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase, ilẹ̀ náà sì di tiwọn. Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun àwọn ọba wọnyi, ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn, láti Baaligadi ní àfonífojì Lẹbanoni títí dé òkè Halaki, ní apá Seiri. Joṣua pín ilẹ̀ wọn fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Ninu ilẹ̀ náà ni àwọn ìlú tí wọ́n wà lórí òkè wà, ati àwọn tí wọ́n wà ní ẹsẹ̀ òkè, ati àwọn tí wọ́n wà ní Araba, ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè, ní aṣálẹ̀, ati ní Nẹgẹbu. Àwọn tí wọ́n ni ilẹ̀ yìí tẹ́lẹ̀ rí ni àwọn ará Hiti ati àwọn ará Amori, àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi, ati àwọn ará Jebusi. Àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun gbogbo ọba àwọn ìlú wọnyi: Jẹriko ati Ai, lẹ́bàá Bẹtẹli; Jerusalẹmu ati Heburoni, Jarimutu ati Lakiṣi; Egiloni ati Geseri, Debiri ati Gederi; Horima ati Aradi, Libina ati Adulamu; Makeda ati Bẹtẹli, Tapua ati Heferi; Afeki ati Laṣaroni, Madoni ati Hasori; Ṣimironi Meroni ati Akiṣafu, Taanaki ati Megido; Kedeṣi ati Jokineamu, ní Kamẹli; Dori, tí ó wà ní etí òkun; Goiimu, tí ó wà ní Galili, ati Tirisa. Gbogbo wọn jẹ́ ọba mọkanlelọgbọn. Ní àkókò yìí, Joṣua ti di àgbàlagbà, ogbó sì ti dé sí i. OLUWA bá sọ fún un pé, “Ogbó ti dé sí ọ, ṣugbọn ilẹ̀ pupọ ni ó kù láti gbà. Ilẹ̀ tí ó kù nìwọ̀nyí: gbogbo agbègbè àwọn ará Filistia ati ti Geṣuri; láti odò Ṣihori, ní apá ìlà oòrùn ilẹ̀ Ijipti, títí lọ sí apá àríwá ní ààlà Ekironi tí ó jẹ́ ti àwọn ará Kenaani, (Marun-un ni ọba àwọn ará Filistia, àwọn nìwọ̀nyí: ọba Gasa, ti Aṣidodu, ti Aṣikeloni, ti Gati, ati ti Ekironi) ati ilẹ̀ àwọn Afimu ní ìhà gúsù. Lẹ́yìn náà, gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Kenaani ati Meara, tíí ṣe ilẹ̀ àwọn ará Sidoni, títí dé Afeki ní ààlà ilẹ̀ àwọn ará Amori, ati ilẹ̀ àwọn ará Gebali, gbogbo Lẹbanoni ní apá ìlà oòrùn, láti Baaligadi tí ó wà ní ìsàlẹ̀ òkè Herimoni títí dé ibodè Hamati. Gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbé àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè, láti Lẹbanoni, títí dé Misirefoti Maimu, ati gbogbo àwọn ará Sidoni ni n óo lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Israẹli. Ṣugbọn, ẹ pín ilẹ̀ náà láàrin àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, bí mo ti pàṣẹ fun yín. Ẹ pín ilẹ̀ náà fún àwọn ẹ̀yà mẹsan-an yòókù ati ìdajì ẹ̀yà Manase.” Ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi, ati ìdajì ẹ̀yà Manase gba ilẹ̀ tí Mose, iranṣẹ OLUWA, fún wọn, tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, ní òdìkejì odò Jọdani; láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Arinoni ati ìlú tí ó wà ní ààrin gbùngbùn àfonífojì náà, ati ilẹ̀ tí ó tẹ́jú ní Medeba títí dé Diboni; ati gbogbo ìlú Sihoni ọba àwọn ará Amori, tí ó jọba ní Heṣiboni, títí kan ààlà àwọn ará Amoni; ati Gileadi ati agbègbè Geṣuri ti Maakati, ati gbogbo òkè Herimoni ati gbogbo Baṣani títí dé Saleka; gbogbo ilẹ̀ ọba Ogu ti Baṣani, tí ó jọba ní Aṣitarotu ati Edirei. Ogu yìí nìkan ṣoṣo ni ó ṣẹ́kù ninu ìran Refaimu yòókù. Mose ti ṣẹgun gbogbo wọn, ó sì ti lé wọn jáde. Sibẹ àwọn ọmọ Israẹli kò lé àwọn ará Geṣuri ati àwọn ará Maakati jáde; wọ́n ń gbé ààrin àwọn ọmọ Israẹli títí di òní olónìí. Ẹ̀yà Lefi nìkan ni Mose kò pín ilẹ̀ fún, ẹbọ tí àwọn ọmọ Israẹli bá rú sí OLUWA ni ìpín tiwọn. Bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. Mose fún àwọn ẹ̀yà Reubẹni ní ilẹ̀, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. Ilẹ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Arinoni, ati ìlú tí ó wà ní ààrin gbùngbùn àfonífojì náà, ati gbogbo ilẹ̀ tí ó tẹ́jú ní Medeba. Pẹlu Heṣiboni ati àwọn ìlú agbègbè rẹ̀ ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú. Àwọn ìlú bíi Diboni, Bamoti Baali, ati Beti Baalimeoni; Jahasi, Kedemotu, ati Mefaati; Kiriataimu, Sibima, ati Sereti Ṣahari, tí ó wà ní orí òkè àfonífojì náà; Betipeori, gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Pisiga, ati Beti Jeṣimotu; àní, àwọn ìlú tí ó wà ní orí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú ati gbogbo ìjọba Sihoni ọba àwọn ará Amori, tí ó jọba ní Heṣiboni, tí Mose ṣẹgun, pẹlu gbogbo àwọn olórí ilẹ̀ Midiani. Àwọn bíi: Efi, Rekemu, Ṣuri, Huru, ati Reba, ọmọ ọba Sihoni, tí ń gbé ilẹ̀ náà. Ọ̀kan ninu àwọn tí àwọn ọmọ Israẹli fi idà pa lójú ogun ni Balaamu, aláfọ̀ṣẹ, ọmọ Beori. Odò Jọdani ni ààlà ilẹ̀ àwọn ẹ̀yà Reubẹni. Àwọn ìlú ńláńlá ati àwọn ìlú kéékèèké tí ó wà ninu ilẹ̀ náà jẹ́ ìpín ẹ̀yà Reubẹni gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. Mose fún ẹ̀yà Gadi ní ìpín tiwọn, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. Ilẹ̀ tiwọn ni Jaseri ati gbogbo ìlú Gileadi, ati ìdajì ilẹ̀ àwọn ará Amoni, títí dé Aroeri tí ó wà ní ìlà oòrùn Raba; láti Heṣiboni, títí dé Ramati Misipe ati Betonimu; ati láti Mahanaimu títí dé agbègbè Debiri; àfonífojì Beti Nimra, Sukotu, ati Safoni, ìyókù ilẹ̀ ìjọba Sihoni, ọba Heṣiboni. Odò Jọdani ni ààlà ilẹ̀ wọn, ní apá ìsàlẹ̀ òkun Kinereti, lọ sí apá ìlà oòrùn, níkọjá odò Jọdani. Àwọn ìlú ńláńlá ati ìlú kéékèèké tí ó wà ninu ilẹ̀ yìí jẹ́ ìpín ẹ̀yà Gadi gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. Mose fún ìdajì ẹ̀yà Manase ní ìpín tiwọn gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. Ilẹ̀ tiwọn bẹ̀rẹ̀ láti Mahanaimu, títí dé gbogbo ilẹ̀ Baṣani, gbogbo ilẹ̀ ìjọba Ogu, ọba Baṣani, ati gbogbo àwọn ìlú Jairi tí ó wà ní Baṣani, gbogbo ìlú wọn jẹ́ ọgọta. Ninu ilẹ̀ wọn ni ìdajì Gileadi wà ati Aṣitarotu ati Edirei, àwọn ìlú ńláńlá ilẹ̀ ìjọba Ogu, ọba Baṣani; Mose pín wọn fún àwọn ìdajì ìdílé Makiri, ọmọ Manase, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. Àkọsílẹ̀ bí Mose ṣe pín ilẹ̀ tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní òdìkejì Jọdani ní apá ìlà oòrùn Jẹriko nìyí. Ṣugbọn Mose kò pín ilẹ̀ fún àwọn ẹ̀yà Lefi, OLUWA Ọlọrun Israẹli ni ìpín tiwọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti wí fún wọn. Àkọsílẹ̀ bí wọn ṣe pín ilẹ̀ Kenaani, tí ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani fún àwọn ọmọ Israẹli nìyí. Eleasari alufaa, Joṣua, ọmọ Nuni, ati àwọn olórí láti inú ìdílé kọ̀ọ̀kan ninu ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n ṣe ètò pípín ilẹ̀ náà. Gègé ni wọ́n ṣẹ́, tí wọ́n fi pín in fún ẹ̀yà mẹsan-an ati ààbọ̀ ninu ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. Nítorí pé Mose ti fún àwọn ẹ̀yà meji ati ààbọ̀ ní ìpín tiwọn ní òdìkejì odò Jọdani, ṣugbọn kò pín ilẹ̀ fún àwọn ẹ̀yà Lefi. Meji ni wọ́n pín àwọn ẹ̀yà Josẹfu sí, àwọn ìpín mejeeji náà ni ẹ̀yà Manase ati ti Efuraimu. Àwọn ẹ̀yà Lefi kò ní ìpín kankan ninu ilẹ̀ náà, ṣugbọn wọ́n fún wọn ní àwọn ìlú láti máa gbé, ati pápá, ibi tí wọ́n ti lè máa da mààlúù wọn, ati gbogbo ẹran ọ̀sìn tí wọ́n ní. Bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose gan-an ni àwọn ọmọ Israẹli ṣe pín ilẹ̀ náà. Ní ọjọ́ kan àwọn ẹ̀yà Juda wá sí ọ̀dọ̀ Joṣua ní Giligali. Ọkunrin kan ninu wọn tí ń jẹ́ Kalebu, ọmọ Jefune, ará Kenisi bá sọ fún un pé, “Ǹjẹ́ o mọ ohun tí OLUWA sọ fún Mose eniyan Ọlọrun ní Kadeṣi Banea nípa àwa mejeeji? Ẹni ogoji ọdún ni mí nígbà tí Mose iranṣẹ OLUWA rán mi láti Kadeṣi Banea láti ṣe amí ilẹ̀ náà. Bí ọkàn mi ti rí gan-an nígbà náà ni mo ṣe ròyìn fún un. Ṣugbọn àwọn arakunrin mi tí a jọ lọ dáyàjá àwọn ọmọ Israẹli, ṣugbọn èmi fi tọkàntọkàn tẹ̀lé OLUWA Ọlọrun mi. Mose bá búra ní ọjọ́ náà pé, ‘Dájúdájú, gbogbo ibi tí ẹsẹ̀ rẹ ti tẹ̀ ni yóo jẹ́ ìpín fún ọ ati fún àwọn ọmọ rẹ títí lae, nítorí pé o ti fi tọkàntọkàn tẹ̀lé OLUWA Ọlọrun mi.’ OLUWA ti dá ẹ̀mí mi sí, gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, láti nǹkan bí ọdún marunlelogoji tí OLUWA ti sọ ọ̀rọ̀ yìí fún Mose nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ń rìn ninu aṣálẹ̀. Nisinsinyii, mo ti di ẹni ọdún marundinlaadọrun, bí agbára mi ṣe rí nígbà tí Mose rán wa jáde láti lọ ṣe amí, bẹ́ẹ̀ náà ni ó wà títí di òní olónìí, mo tún lágbára láti jagun ati láti wọlé ati láti jáde. Nítorí náà, fún mi ní òkè yìí, tí OLUWA sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ọjọ́ náà, nítorí pé ìwọ náà gbọ́ ní ọjọ́ náà pé, àwọn ọmọ Anakimu wà níbẹ̀. Ìlú wọn tóbi, wọ́n sì jẹ́ ìlú olódi, ó ṣeéṣe kí OLUWA wà pẹlu mi kí n sì lè lé wọn jáde, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti wí.” Joṣua bá súre fún Kalebu ọmọ Jefune, ó sì fún un ní òkè Heburoni, bí ìpín tirẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni Heburoni di ilẹ̀ ìní Kalebu, ọmọ Jefune, ará Kenisi títí di òní olónìí, nítorí pé ó fi tọkàntọkàn tẹ̀lé OLUWA Ọlọrun Israẹli. Orúkọ Heburoni tẹ́lẹ̀ ni Kiriati Ariba; Ariba yìí ni ẹni tí ó jẹ́ alágbára jùlọ ninu àwọn òmìrán tí à ń pè ní Anakimu. Àwọn eniyan náà sì sinmi ogun jíjà ní ilẹ̀ náà. Àpèjúwe ìpín tí ó kan ẹ̀yà Juda lára ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli gbà, tí a pín fún wọn gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn nìyí: Ilẹ̀ náà lọ títí dé apá ìhà gúsù, ní ààlà ilẹ̀ Edomu, títí dé aṣálẹ̀ Sini. Ààlà ilẹ̀ wọn, ní ìhà gúsù lọ láti òpin Òkun Iyọ̀, láti apá etí òkun tí ó kọjú sí ìhà gúsù lọ títí dé àtigun òkè Akirabimu. Ó lọ títí dé Sini, ó tún lọ sí apá gúsù Kadeṣi Banea. Ó kọjá lọ lẹ́bàá Hesironi títí dé Adari, kí ó tó wá yípo lọ sí ìhà Kaka. Lẹ́yìn náà, ó lọ títí dé Asimoni, ó tọ ipa odò Ijipti, ó sì pin sí Òkun Mẹditarenia. Òun ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ Juda ní apá ìhà gúsù. Òkun Iyọ̀ ni ààlà ilẹ̀ náà ní apá ìlà oòrùn, ó lọ títí dé ibi tí odò Jọdani ti ń ṣàn wọ inú òkun. Níbẹ̀ ni ààlà rẹ̀ ní apá àríwá ti bẹ̀rẹ̀, ó lọ títí dé Beti Hogila, ó lọ dé ìhà àríwá Betaraba, ó tún lọ títí dé ibi òkúta Bohani ọmọ Reubẹni. Ó lọ láti àfonífojì Akori títí dé Debiri, ó wá yípo lọ sí apá ìhà àríwá, lọ sí Giligali, tí ó dojú kọ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Adumimu, tí ó wà ní apá gúsù àfonífojì náà. Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ibi odò Enṣemeṣi, ó sì pin sí Enrogeli. Ààlà náà tún lọ sí apá òkè, sí àfonífojì ọmọ Hinomu ní apá gúsù òkè àwọn ará Jebusi (tíí ṣe ìlú Jerusalẹmu). Ó tún lọ títí dé orí òkè náà, tí ó dojú kọ àfonífojì ọmọ Hinomu, ní apá ìwọ̀ oòrùn, ní òpin ìhà àríwá àfonífojì Refaimu. Láti ibẹ̀, ó tún bẹ̀rẹ̀ láti orí òkè títí dé odò Nefitoa, ó lọ sí apá ibi tí àwọn ìlú ńláńlá wà lẹ́bàá òkè Efuroni, ó wá pada sí apá Baala (tí a tún ń pè ní Kiriati Jearimu.) Ààlà náà tún yípo lọ sí ìwọ̀ oòrùn Baala, sí apá òkè Seiri, lọ sí apá ìhà àríwá òkè Jearimu (tí a tún ń pè ní Kesaloni), ó bá tún dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ lọ sí Beti Ṣemeṣi títí dé ìkọjá Timna. Ó tún gba ti àwọn òkè tí ó wà ní ìhà àríwá Ekironi, ó wá yípo lọ sí Ṣikeroni. Lẹ́yìn náà, ó kọjá lọ sí òkè Baala títí dé Jabineeli, ó wá lọ parí sí Òkun Mẹditarenia. Òkun yìí ni ààlà ilẹ̀ náà ní apá ìwọ̀ oòrùn. Òun ni ààlà ilẹ̀ àwọn ọmọ Juda gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. Gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Joṣua, ó fún Kalebu ọmọ Jefune ní Heburoni gẹ́gẹ́ bí ìpín tirẹ̀ ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Juda. Orúkọ Heburoni tẹ́lẹ̀ ni Kiriati Ariba, (tí a tún ń pè ní ìlú Ariba), Ariba yìí ni baba Anaki. Kalebu lé àwọn ìran Anaki mẹtẹẹta jáde níbẹ̀, àwọn ni ìran Ṣeṣai, ìran Ahimani, ati ìran Talimai. Láti ibẹ̀ ó lọ gbógun ti àwọn ará ìlú Debiri. Orúkọ Debiri tẹ́lẹ̀ ni Kiriati Seferi. Kalebu ṣe ìlérí pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣẹgun Kiriati Seferi tí ó sì gba ìlú náà ni òun yóo fún ní Akisa ọmọ òun, láti fi ṣe aya. Otinieli ọmọ Kenasi, arakunrin Kalebu, ni ó ṣẹgun ìlú náà. Kalebu bá fi Akisa ọmọ rẹ̀ fún un láti fi ṣe aya. Nígbà tí Akisa dé ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀, ó rọ ọkọ rẹ̀ pé kí ó tọrọ ilẹ̀ kan lọ́wọ́ baba òun. Ní ọjọ́ kan, bí Akisa ti sọ̀kalẹ̀ ní orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, baba rẹ̀ bi í pé, “Kí ni ò ń fẹ́?” Akisa dá baba rẹ̀ lóhùn pé, “Fún mi ní ẹ̀bùn, níwọ̀n ìgbà tí o ti fún mi ní ilẹ̀ Nẹgẹbu, fún mi ní àwọn orísun omi pẹlu.” Kalebu bá fún un ní àwọn orísun omi tí wọ́n wà lókè ati àwọn tí wọ́n wà ní ìsàlẹ̀. Èyí ni ilẹ̀ ẹ̀yà Juda gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn, àwọn ìlú tí ó jẹ́ tiwọn ní ìpẹ̀kun apá ìhà gúsù lẹ́bàá ààlà Edomu nìwọ̀nyí: Kabiseeli, Ederi, Jaguri, Kina, Dimona, Adada, Kedeṣi, Hasori, Itinani; Sifi, Telemu, Bealoti; Hasori Hadata, Kerioti Hesironi (tí a tún ń pè ní Hasori); Amamu, Ṣema, Molada; Hasari Gada, Heṣimoni, Betipeleti; Hasari Ṣuali, Beeriṣeba, Bisiotaya; Baala, Iimu, Esemu; Elitoladi, Kesili, Horima; Sikilagi, Madimana, Sansana; Lebaotu, Ṣilihimu, Aini ati Rimoni; gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mọkandinlọgbọn. Àwọn ìlú wọn tí wọ́n wà ní ẹsẹ̀ òkè nìwọ̀nyí: Eṣitaolu, Sora, Aṣinai. Sanoa, Enganimu, Tapua, Enamu; Jarimutu, Adulamu, Soko, Aseka; Ṣaaraimu, Aditaimu, Gedera, Gederotaimu; gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹrinla. Senani, Hadaṣa, Migidaligadi, Dileani, Misipa, Jokiteeli, Lakiṣi, Bosikati, Egiloni, Kaboni; Lahimami, Kitiliṣi; Gederotu; Beti Dagoni, Naama, ati Makeda; gbogbo ìlú ati ìletò wọ́n jẹ́ mẹrindinlogun. Libina, Eteri, Aṣani, Ifita; Aṣinai, Nesibu, Keila; Akisibu, ati Mareṣa; gbogbo ìlú ati ìletò wọ́n jẹ́ mẹsan-an. Ekironi pẹlu àwọn ìlú ati ìletò rẹ̀; láti Ekironi títí dé etí òkun Mẹditarenia, ati gbogbo àwọn ìlú tí wọ́n wà lẹ́bàá Aṣidodu pẹlu àwọn ìletò wọn. Aṣidodu, pẹlu àwọn ìlú ati àwọn ìletò rẹ̀; Gasa, pẹlu àwọn ìlú ati àwọn ìletò rẹ̀ títí dé odò Ijipti, ati etí òkun Mẹditarenia, pẹlu agbègbè rẹ̀. Àwọn ìlú tí wọ́n wà ní orí òkè nìwọ̀nyí: Ṣamiri, Jatiri, Soko, Dana, Kiriati Seferi (tí à ń pè ní Debiri), Anabu, Eṣitemoa, Animi, Goṣeni, Holoni, ati Gilo; gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mọkanla. Arabu, Duma, Eṣani, Janimu, Beti Tapua, Afeka, Humita, Kiriati Ariba (tí à ń pè ní Heburoni), ati Siori, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹsan-an. Maoni, Kamẹli, Sifi, Juta. Jesireeli, Jokideamu, Sanoa, Kaini, Gibea, ati Timna, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹ́wàá. Halihuli, Betisuri, Gedori, Maarati, Betanotu, ati Elitekoni, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹfa. Kiriati Baali (tí wọn ń pè ní Kiriati Jearimu), ati Raba, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ meji. Àwọn ìlú tí wọ́n wà ní aṣálẹ̀ ni, Betaraba, Midini, Sekaka; Nibiṣani, Ìlú Iyọ̀, ati Engedi; gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹfa. Ṣugbọn àwọn eniyan Juda kò lè lé àwọn Jebusi tí wọn ń gbé inú ilẹ̀ Jerusalẹmu jáde. Àwọn Jebusi yìí sì tún wà láàrin àwọn eniyan Juda ní Jerusalẹmu títí di òní olónìí. Ààlà ilẹ̀ tí wọ́n pín fún àwọn ọmọ Josẹfu bẹ̀rẹ̀ láti odò Jọdani lẹ́bàá Jẹriko, ní apá ìlà oòrùn àwọn odò Jẹriko, ó lọ títí dé apá aṣálẹ̀. Ó tún bẹ̀rẹ̀ láti Jẹriko lọ sí apá àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè, títí dé Bẹtẹli. Láti Bẹtẹli, ó lọ sí Lusi, ó sì kọjá lọ sí Atarotu, níbi tí àwọn ọmọ Ariki ń gbé. Bákan náà ni ó tún lọ sí ìsàlẹ̀ ní apá ìwọ̀ oòrùn títí dé agbègbè àwọn ará Jafileti, títí dé apá ìsàlẹ̀ Beti Horoni. Ó tún lọ láti ibẹ̀ títí dé Geseri, ó sì pin sí Òkun Mẹditarenia. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Josẹfu, tí à ń pè ní ẹ̀yà Manase ati ẹ̀yà Efuraimu ṣe gba ìpín tiwọn. Èyí ni ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Efuraimu gbà, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. Ààlà ilẹ̀ wọn ní apá ìlà oòrùn bẹ̀rẹ̀ láti Atarotu Adari, títí dé apá òkè Beti Horoni. Láti ibẹ̀ ó lọ títí dé Òkun Mẹditarenia. Mikimetati ni ààlà wọn ní ìhà àríwá. Ní apá ìlà oòrùn ibẹ̀, ààlà ilẹ̀ wọn yípo lọ sí apá Taanati Ṣilo, ó sì kọjá ibẹ̀ lọ ní ìhà ìlà oòrùn lọ sí Janoa. Lẹ́yìn náà, ní ìsàlẹ̀, láti Janoa, lọ sí Atarotu ati Naara. Ó lọ títí dé Jẹriko, ó sì pin sí odò Jọdani. Láti Tapua, ààlà náà lọ sí apá ìwọ̀ oòrùn títí dé odò Kana, ó sì pin sí Òkun Mẹditarenia. Èyí ni ilẹ̀ tí wọ́n pín fún ẹ̀yà Efuraimu gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn, pẹlu àwọn ìlú ati àwọn ìletò wọn tí ó wà ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Manase, ṣugbọn tí a fi fún ẹ̀yà Efuraimu. Ṣugbọn wọn kò lé àwọn ará Kenaani tí ń gbé Geseri jáde, nítorí náà, àwọn ará Kenaani ń gbé ààrin ẹ̀yà Efuraimu títí di òní olónìí. Ẹ̀yà Efuraimu ń fi tipátipá mú wọn ṣiṣẹ́ bí ẹrú. Wọ́n pín ilẹ̀ fún ẹ̀yà Manase nítorí pé ó jẹ́ àkọ́bí Josẹfu. Makiri, baba Gileadi, tí ó jẹ́ àkọ́bí Manase ni wọ́n fún ní ilẹ̀ Gileadi ati Baṣani nítorí pé ó jẹ́ akọni ati akikanju eniyan. Wọ́n fún àwọn ìdílé Manase yòókù ní ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn: àwọn bíi Abieseri, Heleki, Asirieli, Ṣekemu, Heferi, ati Ṣemida. Àwọn ni ọmọkunrin Manase, tíí ṣe ọmọ Josẹfu; wọ́n sì jẹ́ olórí fún àwọn ìdílé wọn. Selofehadi, ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manase, kò ní ọmọkunrin rárá, àfi kìkì ọmọbinrin. Orúkọ wọn ni Mahila, Noa, Hogila, Milika, ati Tirisa. Wọ́n tọ Eleasari, alufaa, ati Joṣua ọmọ Nuni, ati àwọn àgbààgbà lọ, wọ́n wí fún wọn pé, “OLUWA ti pàṣẹ fún Mose pé kí ó pín ilẹ̀ fún àwa náà, gẹ́gẹ́ bí ó ti pín fún àwọn ìbátan wa, tí wọ́n jẹ́ ọkunrin.” Nítorí náà bí OLUWA ti pa á láṣẹ, wọ́n pín ilẹ̀ fún àwọn náà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti pín fún àwọn ìbátan wọn tí wọ́n jẹ́ ọkunrin. Ìdí nìyí tí ìpín mẹ́wàá fi kan Manase láìka Gileadi, ati Baṣani ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani. Nítorí pé àwọn ọmọbinrin Manase gba ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ìbátan wọn tí wọ́n jẹ́ ọkunrin. Wọ́n pín ilẹ̀ Gileadi fún àwọn ọmọ Manase yòókù. Ilẹ̀ ti Manase bẹ̀rẹ̀ láti Aṣeri títí dé Mikimetati tí ó wà ní apá ìlà oòrùn Ṣekemu, ààlà rẹ̀ tún lọ sí apá ìhà gúsù ní apá ọ̀dọ̀ àwọn tí wọn ń gbé Entapua. Àwọn ọmọ Manase ni wọ́n ni ilẹ̀ Tapua, ṣugbọn ìlú Tapua gan-an, tí ó wà ní ààlà ilẹ̀ àwọn ọmọ Manase, jẹ́ ti àwọn ọmọ Efuraimu. Ààlà ilẹ̀ wọn tún lọ sí apá ìsàlẹ̀ títí dé odò Kana, àwọn ìlú wọnyi tí wọ́n wà ní apá gúsù odò náà, láàrin ìlú àwọn ọmọ Manase, jẹ́ ti àwọn ọmọ Efuraimu. Ààlà àwọn ọmọ Manase tún lọ sí apá àríwá odò náà, ó sì pin sí Òkun Mẹditarenia. Ilẹ̀ tí ó wà ní apá ìhà gúsù jẹ́ ti àwọn ọmọ Efuraimu, èyí tí ó wà ní apá ìhà àríwá jẹ́ ti àwọn ọmọ Manase. Òkun Mẹditarenia ni ààlà wọn ní apá ìwọ̀ oòrùn. Ní apá ìhà àríwá, ilẹ̀ wọn lọ títí kan ilẹ̀ ẹ̀yà Aṣeri, ó sì kan ti ẹ̀yà Isakari ní apá ìlà oòrùn. Ní ilẹ̀ Isakari, ati ti Aṣeri, àwọn ọmọ Manase ni wọ́n ni ìlú Beti Ṣeani ati àwọn ìletò tí wọ́n wà ní agbègbè rẹ̀, Ibileamu ati àwọn ìletò tí wọ́n wà ní agbègbè rẹ̀, ati Dori, Endori, Taanaki ati Megido ati gbogbo àwọn ìletò tí wọ́n wà ní agbègbè wọn. Àwọn náà ni wọ́n ni Nafati. Ṣugbọn àwọn ọmọ Manase kò lè gba àwọn ìlú náà, àwọn ará Kenaani sì ń gbé ilẹ̀ náà. Ṣugbọn nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli di alágbára, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi tipátipá mú àwọn ará Kenaani sìn, wọn kò sì lé wọn jáde patapata. Àwọn ẹ̀yà Josẹfu lọ bá Joṣua, wọ́n wí fún un pé, “Kí ló dé tí o fi fún wa ní ẹyọ ilẹ̀ kan ṣoṣo gẹ́gẹ́ bí ìpín tiwa, nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn eniyan wa pọ̀ gan-an, nítorí pé OLUWA ti bukun wa?” Joṣua dá wọn lóhùn, ó ní, “Bí ẹ bá pọ̀, ẹ lọ sí inú igbó, kí ẹ sì gba ilẹ̀ níbẹ̀ ninu ilẹ̀ àwọn ará Perisi ati ti àwọn Refaimu, bí ilẹ̀ olókè ti Efuraimu kò bá tóbi tó fun yín.” Àwọn ẹ̀yà Josẹfu bá dáhùn pé, “Ilẹ̀ olókè yìí kò tó fún wa, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Kenaani tí ń gbé pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní kẹ̀kẹ́ ogun tí wọ́n fi irin ṣe, bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn tí wọn ń gbé Beti Ṣani, ati àwọn ìletò tí ó wà ní agbègbè rẹ̀, ati àwọn tí ń gbé àfonífojì Jesireeli.” Joṣua bá dá àwọn ọmọ Josẹfu: ẹ̀yà Efuraimu ati ti Manase lóhùn, ó ní, “Ẹ pọ̀ nítòótọ́, ẹ sì ní agbára, ilẹ̀ kan ṣoṣo kọ́ ni yóo kàn yín, ẹ̀yin ni ẹ óo ni agbègbè olókè wọnyi pẹlu. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igbó ni, ẹ gbà á, kí ẹ sì ṣán an láti òkè dé ilẹ̀ títí dé òpin ààlà rẹ̀. Ẹ óo lé àwọn ará Kenaani jáde, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé irin ni wọ́n fi ṣe kẹ̀kẹ́ ogun wọn, tí wọ́n sì jẹ́ alágbára.” Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Israẹli ti ṣẹgun ilẹ̀ náà, gbogbo wọn péjọ sí Ṣilo, wọ́n sì pa àgọ́ àjọ níbẹ̀. Ó ku ẹ̀yà meje, ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli, tí wọn kò tíì pín ilẹ̀ fún. Joṣua bá sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ìgbà wo ni ẹ fẹ́ dúró dà kí ẹ tó lọ gba ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín ti fun yín. Ẹ yan eniyan mẹta mẹta wá láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, n óo sì rán wọn jáde lọ láti rin ilẹ̀ náà jákèjádò, kí wọ́n lè ṣe àkọsílẹ̀ ibi tí wọ́n bá fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpín tiwọn, lẹ́yìn náà, kí wọ́n pada wá jíyìn fún mi. Ọ̀nà meje ni wọn yóo pín ilẹ̀ náà sí, àwọn ẹ̀yà Juda kò ní kúrò ní àyè tiwọn ní apá ìhà gúsù, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹ̀yà Josẹfu tí wọ́n wà ní agbègbè tiwọn ní apá ìhà àríwá. Ẹ óo ṣe àkọsílẹ̀ ìpín mejeeje, ẹ óo sì mú un tọ̀ mí wá. N óo ba yín ṣẹ́ gègé lórí wọn níhìn-ín, níwájú OLUWA Ọlọrun wa. Àwọn ẹ̀yà Lefi kò ní ba yín pín ilẹ̀ nítorí iṣẹ́ alufaa OLUWA ni ìpín tiwọn. Ẹ̀yà Gadi ati ti Reubẹni ati ìdajì ẹ̀yà Manase ti gba ìpín tiwọn tí Mose, iranṣẹ OLUWA, fún wọn ní apá ìlà oòrùn, ní òdìkejì odò Jọdani.” Àwọn ọkunrin náà bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn, Joṣua sì kìlọ̀ fún wọn, pé, “Ẹ rin ilẹ̀ náà jákèjádò, kí ẹ sì kọ àpèjúwe rẹ̀ sílẹ̀ wá fún mi. N óo sì ba yín ṣẹ́ gègé níhìn-ín níwájú OLUWA ní Ṣilo.” Àwọn ọkunrin náà bá lọ, wọ́n rin ilẹ̀ náà jákèjádò, wọ́n sì ṣe àkọsílẹ̀ àpèjúwe àwọn ìlú tí wọ́n wà ninu rẹ̀ ní ìsọ̀rí meje sinu ìwé kan, wọ́n pada wá sí ọ̀dọ̀ Joṣua ninu àgọ́ ní Ṣilo. Joṣua bá bá wọn ṣẹ́ gègé ní Ṣilo, níwájú OLUWA, bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ṣe pín ilẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli. Ó fún ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní ìpín tirẹ̀. Ìpín ti ẹ̀yà Bẹnjamini gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn wà ní ààrin ilẹ̀ ẹ̀yà Juda ati ti ẹ̀yà Josẹfu. Ní apá ìhà àríwá, ààlà ilẹ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ ní etí odò Jọdani, lọ sí ara òkè ní ìhà àríwá Jẹriko. Ó gba ààrin àwọn ìlú tí wọ́n wà ní orí òkè lọ ní apá ìwọ̀ oòrùn, ó sì pin sí aṣálẹ̀ Betafeni. Láti ibẹ̀ ààlà ilẹ̀ náà gba apá ìhà gúsù, ní ọ̀nà Lusi, kọjá lọ sí ara òkè, (Lusi ni wọ́n ń pè ní Bẹtẹli tẹ́lẹ̀) ààlà náà tún yípo lọ sí apá ìsàlẹ̀, sí ọ̀nà Atarotu Adari, sí orí òkè tí ó wà ní apá ìhà gúsù, ni ìsàlẹ̀ Beti Horoni. Ó tún yípo lọ ní apá ìwọ̀ oòrùn, sí apá ìhà gúsù lọ sí ara àwọn òkè tí ó wà ní apá ìhà gúsù tí ó dojú kọ Beti Horoni, ó sì pin sí Kiriati Baali (tí wọ́n tún ń pè ní Kiriati Jearimu), ọ̀kan ninu àwọn ìlú ẹ̀yà Juda. Èyí ni apá ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ náà. Ààlà ti apá ìhà gúsù ilẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ ní àtiwọ ìlú Kiriati Jearimu lọ títí dé Efuroni, títí dé odò Nefitoa, kí ó tó yípo lọ sí ìsàlẹ̀, sí ẹsẹ̀ òkè tí ó dojú kọ àfonífojì ọmọ Hinomu, níbi tí àfonífojì Refaimu pin sí ní ìhà àríwá. Ààlà náà la àfonífojì Hinomu kọjá lọ sí apá ìhà gúsù ní etí Jebusi, ó tún lọ sí ìsàlẹ̀ títí dé Enrogeli. Lẹ́yìn náà, ó yípo lọ sí apá àríwá, kí ó tó wa lọ sí Enṣemeṣi títí lọ dé Gelilotu tí ó dojú kọ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Adumimu, lẹ́yìn náà ó wá sí ìsàlẹ̀ ní ibi tí òkúta Bohani ọmọ Reubẹni wà. Ààlà náà kọjá lọ sí apá ìhà àríwá òkè Betaraba; láti ibẹ̀ ó lọ sí Araba. Ó tún lọ sí apá ìhà àríwá òkè Beti Hogila, kí ó tó wá lọ sí apá etí Òkun Iyọ̀, níbi tí ó ti lọ fi orí sọ òpin odò Jọdani, ní ìhà gúsù. Ó jẹ́ ààlà ilẹ̀ ẹ̀yà Bẹnjamini ní apá ìhà gúsù. Odò Jọdani ni ààlà rẹ̀ ní apá ìlà oòrùn. Èyí ni ilẹ̀ tí a pín fún ẹ̀yà Bẹnjamini ní ìdílé-ìdílé, pẹlu àwọn ààlà ilẹ̀ ìdílé kọ̀ọ̀kan. Àwọn ìlú tí ó wà ní ilẹ̀ náà ni: Jẹriko, Beti Hogila, Emeki Kesisi; Betaraba, Semaraimu, Bẹtẹli; Afimu, Para, Ofira; Kefariamoni, Ofini, ati Geba; gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mejila. Gibeoni, Rama, Beeroti Misipa, Kefira, Mosa; Rekemu, Iripeeli, Tarala; Sela, Haelefi, Jebusi (tí à ń pè ní Jerusalẹmu) Gibea, ati Kiriati Jearimu, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹrinla. Ilẹ̀ náà jẹ́ ìpín ti ẹ̀yà Bẹnjamini, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. Ilẹ̀ keji tí wọ́n ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ ẹ̀yà Simeoni, ilẹ̀ tiwọn bọ́ sí ààrin ìpín ti ẹ̀yà Juda. Àwọn ìlú tí ó wà ninu ilẹ̀ tí wọ́n pín fún wọn nìyí: Beeriṣeba, Ṣeba, Molada; Hasari Ṣuali, Bala, Esemu; Elitoladi, Betuli, Horima, Sikilagi, Beti Makabotu, ati Hasari Susa; Beti Lebaotu ati Ṣaruheni, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹtala. Enrimoni, Eteri, ati Aṣani, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹrin, pẹlu gbogbo àwọn ìletò tí ó yí àwọn ìlú ńláńlá wọnyi ká títí dé Baalati Beeri, (tí wọ́n ń pè ní Rama) tí ó wà ní Nẹgẹbu ní ìhà gúsù. Òun ni ìpín ti ẹ̀yà Simeoni, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. Apá kan ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Juda jẹ́ ìpín ti ẹ̀yà Simeoni. Ìpín ti ẹ̀yà Juda tóbi jù fún wọn, nítorí náà ni ẹ̀yà Simeoni ṣe mú ninu tiwọn. Ilẹ̀ kẹta tí wọ́n ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ ẹ̀yà Sebuluni. Agbègbè tí ó jẹ́ ìpín tiwọn lọ títí dé Saridi. Níbẹ̀ ni ààlà ilẹ̀ wọn ti yípo lọ sókè sí apá ìwọ̀ oòrùn, ó sì wá sí apá ìlà oòrùn Jokineamu. Láti Saridi, ààlà ilẹ̀ náà lọ sí òdìkejì, ní ìhà ìlà oòrùn, títí dé ààlà Kisiloti Tabori, láti ibẹ̀, ó lọ sí Daberati títí lọ sí Jafia; láti Jafia, ó lọ sí apá ìlà oòrùn títí dé Gati Heferi ati Etikasini, nígbà tí ó dé Rimoni, ó yípo lọ sí apá Nea. Ní apá ìhà àríwá, ààlà náà yípo lọ sí Hanatoni, ó sì pin sí àfonífojì Ifitaeli. Ara àwọn ìlú tí ó wà níbẹ̀ ni, Kata, Nahalali, Ṣimironi, Idala, ati Bẹtilẹhẹmu, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mejila. Àwọn ni ìlú ati ìletò tí ó wà ninu ilẹ̀ tí ó kan ẹ̀yà Sebuluni gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. Ilẹ̀ kẹrin tí wọ́n ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ ẹ̀yà Isakari. Lórí ilẹ̀ náà ni àwọn ìlú wọnyi wà: Jesireeli, Kesuloti, Ṣunemu; Hafaraimu, Sihoni, Anaharati; Rabiti, Kiṣioni, Ebesi; Remeti, Enganimu, Enhada, ati Betipasesi. Ààlà ilẹ̀ náà lọ kan Tabori, Ṣahasuma ati Beti Ṣemeṣi, kí ó tó lọ pin sí odò Jọdani. Gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹrindinlogun. Àwọn ni ìlú ati ìletò náà tí ó wà ninu ilẹ̀ tí ó kan ẹ̀yà Isakari gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. Ilẹ̀ karun-un tí wọ́n ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ ẹ̀yà Aṣeri. Ninu ilẹ̀ náà ni àwọn ìlú wọnyi wà: Helikati, Hali, Beteni, Akiṣafu. Alameleki, Amadi, ati Miṣali, ní apá ìwọ̀ oòrùn, ilẹ̀ náà dé Kamẹli ati Ṣihori Libinati. Ààlà rẹ̀ wá yípo lọ sí apá ìlà oòrùn, títí dé Beti Dagoni, títí dé Sebuluni ati àfonífojì Ifitaeli ní apá àríwá Betemeki ati Neieli. Lẹ́yìn náà ó tún lọ ní apá ìhà àríwá náà títí dé Kabulu, Eburoni, Rehobu, Hamoni, ati Kana, títí dé Sidoni Ńlá; Lẹ́yìn náà, ààlà náà yípo lọ sí Rama; ó dé ìlú olódi ti Tire, lẹ́yìn náà, ó yípo lọ sí Hosa, ó sì pin sí etíkun. Ninu ilẹ̀ wọn ni Mahalabu, Akisibu; Uma, Afeki, ati Rehobu wà, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mejilelogun. Àwọn ni ìlú ati ìletò tí ó wà ninu ilẹ̀ tí ó kan ẹ̀yà Aṣeri gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. Ilẹ̀ kẹfa tí wọ́n ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ ẹ̀yà Nafutali, Ààlà ilẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ ní Helefi, láti ibi igi oaku tí ó wà ní Saananimu, Adaminekebu, ati Jabineeli, títí dé Lakumu, ó sì pin sí odò Jọdani. Níbẹ̀ ni ààlà náà ti yipada lọ sí apá ìwọ̀ oòrùn sí Asinotu Tabori. Láti ibẹ̀, ó lọ títí dé Hukoku, ó lọ kan ilẹ̀ ẹ̀yà Sebuluni ní apá ìhà gúsù, ó sì kan ilẹ̀ ẹ̀yà Aṣeri lápá ìwọ̀ oòrùn, ati ti Juda ní apá ìlà oòrùn létí odò Jọdani. Àwọn ìlú olódi tí ó wà ní ilẹ̀ náà ni Sidimu, Seri, Hamati, Rakati, Kinereti; Adama, Rama, Hasori; Kedeṣi, Edirei, Enhasoru, Yironi, Migidalieli, Horemu, Betanati ati Beti Ṣemeṣi, gbogbo ìlú ati àwọn ìletò wọn jẹ́ mọkandinlogun. Àwọn ni ìlú ati ìletò tí ó wà ninu ilẹ̀ tí ó kan ẹ̀yà Nafutali gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. Ilẹ̀ keje tí wọ́n ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ ẹ̀yà Dani. Ninu ilẹ̀ náà ni àwọn ìlú wọnyi wà: Sora, Ẹṣitaolu, Iriṣemeṣi; Ṣaalibimu, Aijaloni, Itila, Eloni, Timna, Ekironi, Eliteke, Gibetoni, Baalati; Jehudi, Beneberaki, Gati Rimoni ati Mejakoni, ati Rakoni pẹlu agbègbè tí ó dojú kọ Jọpa. Nígbà tí ilẹ̀ ẹ̀yà Dani bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́, wọ́n bá lọ gbógun ti ìlú Leṣemu, wọ́n ṣẹgun wọn, wọ́n pa wọ́n, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn. Wọ́n yí orúkọ Leṣemu pada sí Dani, tíí ṣe orúkọ baba ńlá wọn, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. Àwọn ìlú ati àwọn ìletò wọnyi ni ìpín tí ó kan ẹ̀yà Dani gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli pín gbogbo agbègbè tí ó wà ninu ilẹ̀ náà ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan tán, wọ́n pín ilẹ̀ fún Joṣua ọmọ Nuni pẹlu. Wọ́n fún un ní ilẹ̀ tí ó bèèrè fún gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA. Ìlú tí ó bèèrè fún ni Timnati Sera ní agbègbè olókè ti Efuraimu, ó tún ìlú náà kọ́, ó sì ń gbé ibẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni Eleasari alufaa ati Joṣua ọmọ Nuni ati àwọn àgbààgbà ninu ẹ̀yà àwọn eniyan Israẹli ṣe ṣẹ́ gègé láti pín ilẹ̀ náà ní Ṣilo níwájú OLUWA, ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé; wọ́n sì parí pípín ilẹ̀ náà. Lẹ́yìn náà, OLUWA sọ fún Joṣua pé, “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n yan àwọn ìlú ààbò tí mo bá Mose sọ nípa rẹ̀, pé kí ó sọ fun yín. Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì pa eniyan lè sá lọ sibẹ. Ibẹ̀ ni yóo jẹ́ ibi ààbò fun yín tí ọwọ́ ẹni tí ń gbẹ̀san ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ kò fi ní máa tẹ̀ yín. Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì pa eniyan sá lọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú ọ̀hún, kí ó dúró ní ẹnubodè ìlú, kí ó sì ro ẹjọ́ fún àwọn àgbààgbà ibẹ̀. Wọn yóo mú un wọ inú ìlú lọ, wọn yóo fún un ní ibi tí yóo máa gbé, yóo sì wà ní ọ̀dọ̀ wọn. Bí ẹni tí ń gbẹ̀san ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ bá ń lé e bọ̀, wọn kò ní fi lé e lọ́wọ́, nítorí pé ó ṣèèṣì pa aládùúgbò rẹ̀ ni, kò sì ní ìkùnsínú sí i tẹ́lẹ̀. Ìlú yìí ni yóo máa gbé títí tí àwọn ìgbìmọ̀ yóo fi ṣe ìdájọ́ rẹ̀, yóo máa gbé ibẹ̀ títí tí ẹni tí ó jẹ́ olórí alufaa ní àkókò náà yóo fi kú, lẹ́yìn náà ẹni tí ó ṣèèṣì pa eniyan yìí lè pada lọ sí ilé rẹ̀ ati sí ìlú rẹ̀ níbi tí ó ti sá wá.” Wọ́n ya Kedeṣi sọ́tọ̀ ní Galili ní agbègbè olókè ti Nafutali, ati Ṣekemu ní agbègbè olókè ti Efuraimu, ati Kiriati Ariba (tí wọ́n ń pè ní Heburoni), ní agbègbè olókè ti Juda. Ní òdìkejì odò Jọdani, ní apá ìlà oòrùn Jẹriko, wọ́n ya Beseri tí ó wà ninu aṣálẹ̀ ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú sọ́tọ̀. Wọ́n ya Ramoti tí ó wà ní Gileadi sọ́tọ̀ ní agbègbè ti ẹ̀yà Gadi, ati Golani tí ó wà ní Baṣani, ní agbègbè ti ẹ̀yà Manase. Àwọn ìlú ọ̀hún ni ìlú ààbò tí wọ́n yàn fún àwọn ọmọ Israẹli, ati fún àwọn àlejò tí wọ́n ń gbé ààrin wọn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì pa eniyan lè sá lọ sí èyíkéyìí ninu wọn, yóo sì bọ́ lọ́wọ́ ẹni tí ń gbẹ̀san ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ títí tí àwọn ìgbìmọ̀ yóo fi ṣe ìdájọ́ rẹ̀. Lẹ́yìn náà àwọn olórí ìdílé ninu ẹ̀yà Lefi wá sí ọ̀dọ̀ Eleasari alufaa, ati sí ọ̀dọ̀ Joṣua ọmọ Nuni, ati àwọn olórí ìdílé ní gbogbo ẹ̀yà Israẹli, ní Ṣilo ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n sọ fún wọn pé, “OLUWA ti pàṣẹ láti ẹnu Mose pé kí wọ́n fún wa ní ìlú tí a óo máa gbé ati pápá oko fún àwọn ẹran ọ̀sìn wa.” Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA, àwọn ọmọ Israẹli fún àwọn ọmọ Lefi ní àwọn ìlú ati pápá tí ó yí wọn ká, ninu ilẹ̀ ìní wọn. Ilẹ̀ kinni tí wọ́n kọ́kọ́ ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọmọ Kohati. Nítorí náà, gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n jẹ́ ìran Aaroni alufaa gba ìlú mẹtala lọ́wọ́ àwọn ẹ̀yà Juda, ẹ̀yà Simeoni, ati ẹ̀yà Bẹnjamini. Àwọn ọmọ Kohati yòókù sì gba ìlú mẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn ẹ̀yà Efuraimu, ẹ̀yà Dani, ati ìdajì ẹ̀yà Manase. Àwọn ọmọ Geriṣoni gba ìlú mẹtala lọ́wọ́ àwọn ẹ̀yà Isakari, ẹ̀yà Aṣeri, ẹ̀yà Nafutali, ati ìdajì ẹ̀yà Manase tí wọ́n wà ní Baṣani. Àwọn ọmọ Merari gba ìlú mejila lọ́wọ́ àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ẹ̀yà Sebuluni. Àwọn ìlú náà ati pápá oko wọn ni àwọn ọmọ Israẹli fún àwọn ọmọ Lefi, lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣẹ́ gègé lé wọn lórí, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ láti ẹnu Mose. Àwọn ẹ̀yà Juda ati ẹ̀yà Simeoni fi àwọn ìlú náà sílẹ̀ fún àwọn ọmọ Lefi, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Kohati, tíí ṣe ìran Aaroni, nítorí pé àwọn ni gègé kọ́kọ́ mú. Àwọn ni wọ́n fún ní Kiriati Ariba tí wọ́n ń pè ní ìlú Heburoni lónìí, (Ariba yìí ni baba Anaki), ati àwọn pápá ìdaran tí wọ́n wà ní àyíká rẹ̀ ní agbègbè olókè ti Juda. Ṣugbọn àwọn oko tí wọ́n yí ìlú náà ká ati àwọn ìletò rẹ̀ ni wọ́n fi fún Kalebu ọmọ Jefune gẹ́gẹ́ bí ìpín tirẹ̀. Àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, ni wọ́n fún ní ìlú Heburoni, tíí ṣe ìlú ààbò fún àwọn tí wọ́n bá ṣèèṣì pa eniyan, pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká rẹ̀, ati ìlú Libina pẹlu àwọn pápá ìdaran tí wọ́n wà ní àyíká rẹ̀. Ati àwọn ìlú wọnyi pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn: Jatiri, Eṣitemoa, Holoni, Debiri; Aini, Juta, ati Beti Ṣemeṣi, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹsan-an ní ààrin ilẹ̀ àwọn ẹ̀yà mejeeji. Láàrin ilẹ̀ ẹ̀yà Bẹnjamini, wọ́n fún àwọn ọmọ Lefi ní àwọn ìlú wọnyi pẹlu pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn: Gibeoni, Geba, Anatoti ati Alimoni, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin. Àwọn ìlú tí wọ́n fún àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, jẹ́ mẹtala pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn. Láti inú ilẹ̀ ẹ̀yà Efuraimu ni wọ́n ti gba ìlú fún àwọn ọmọ Kohati yòókù, tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà Lefi. Àwọn ni wọ́n fún ní ìlú Ṣekemu, tí ó jẹ́ ìlú ààbò fún àwọn tí wọ́n bá ṣèèṣì pa eniyan, ati àwọn pápá ìdaran rẹ̀ tí ó wà ní agbègbè olókè ti Efuraimu. Wọ́n tún fún wọn ní àwọn ìlú wọnyi, pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn: Geseri, Kibusaimu ati Beti Horoni, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin. Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Dani, wọ́n fún wọn ní àwọn ìlú wọnyi pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn: Eliteke, Gibetoni. Aijaloni ati Gati Rimoni, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin. Ninu ilẹ̀ ìdajì ẹ̀yà Manase, wọ́n fún wọn ní àwọn ìlú wọnyi pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn: Taanaki, ati Gati Rimoni, wọ́n jẹ́ ìlú meji. Ìlú àwọn ọmọ Kohati yòókù jẹ́ mẹ́wàá pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn. Ninu ilẹ̀ ìdajì ẹ̀yà Manase ni wọ́n ti fún àwọn ọmọ Geriṣoni ninu ìdílé Lefi ní àwọn ìlú wọnyi: Golani ní ilẹ̀ Baṣani pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká rẹ̀. Golani yìí jẹ́ ìlú ààbò fún àwọn tí wọ́n bá ṣèèṣì pa eniyan, ati Beeṣitera pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká rẹ̀, wọ́n jẹ́ ìlú meji. Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Isakari, wọ́n fún wọn ní: Kiṣioni, Daberati, ati Jarimutu, Enganimu pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin. Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Aṣeri, wọ́n fún wọn ní: Miṣali, Abidoni, Helikati, ati Rehobu pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin. Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Nafutali, wọ́n fún wọn ní: Kedeṣi ní Galili. Kedeṣi yìí jẹ́ ìlú ààbò fún àwọn tí wọ́n bá ṣèèṣì pa eniyan, wọ́n tún fún wọn ní Hamoti Dori, Katani pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹta. Ìlú mẹtala ati pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn ni ilẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Geriṣoni, gẹ́gẹ́ bi iye ìdílé wọn. Ìdílé tí ó ṣẹ́kù ninu ẹ̀yà Lefi ni ìdílé Merari. Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Sebuluni, wọ́n fún wọn ní: Jokineamu, Kata, Dimna, Nahalali pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin. Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Reubẹni, wọ́n fún wọn ní: Beseri, Jahasi, Kedemotu, ati Mefaati pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin. Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Gadi, wọ́n fún wọn ní: Ramoti ní Gileadi. Ramoti yìí ni ìlú ààbò fún àwọn tí wọ́n bá ṣèèṣì pa eniyan. Wọ́n tún fún wọn ní Mahanaimu, Heṣiboni, ati Jaseri pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin. Ìlú mejila ni wọ́n fún àwọn ìdílé yòókù ninu ẹ̀yà Lefi tí à ń pè ní Merari gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. Gbogbo ìlú tí wọ́n fún àwọn ọmọ Lefi ninu ilẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli jẹ́ mejidinlaadọta pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn. Olukuluku àwọn ìlú yìí ní pápá ìdaran tí ó yí i ká, bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn ìlú yòókù. Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe fún àwọn ọmọ Israẹli ní ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba wọn. Lẹ́yìn tí wọ́n gba ilẹ̀ náà tán, wọ́n ń gbé ibẹ̀. OLUWA fún wọn ní ìsinmi ní gbogbo àyíká wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún àwọn baba wọn. Kò sì sí èyíkéyìí ninu àwọn ọ̀tá wọn tí ó lè ṣẹgun wọn, nítorí pé OLUWA ti fi gbogbo àwọn ọ̀tá wọn lé wọn lọ́wọ́. Ninu gbogbo ìlérí dáradára tí OLUWA ṣe fún ilé Israẹli kò sí èyí tí kò mú ṣẹ; gbogbo wọn patapata ni ó mú ṣẹ. Lẹ́yìn náà, Joṣua pe àwọn ẹ̀yà Reubẹni ati ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase, ó wí fún wọn pé, “Gbogbo ohun tí Mose, iranṣẹ OLUWA pa láṣẹ fun yín ni ẹ ti ṣe; ẹ sì ti ṣe gbogbo ohun tí èmi náà pa láṣẹ fun yín. Ẹ kò kọ àwọn arakunrin yín sílẹ̀ láti ọjọ́ yìí wá títí di òní, ṣugbọn ẹ fara balẹ̀, ẹ sì ti ń pa gbogbo àṣẹ OLUWA Ọlọrun yín mọ́. Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun yín ti fún àwọn arakunrin yín ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí fún wọn; nítorí náà, ẹ pada lọ sí ilẹ̀ yín, níbi tí ohun ìní yín wà, àní ilẹ̀ tí Mose iranṣẹ OLUWA fun yín ní òdìkejì odò Jọdani. Ẹ máa ranti lemọ́lemọ́ láti máa pa gbogbo òfin tí Mose iranṣẹ OLUWA fun yín mọ́, pé kí ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, kí ẹ sì máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀, ẹ máa pa gbogbo òfin rẹ̀ mọ́, ẹ súnmọ́ ọn, kí ẹ sì máa sìn ín tọkàntọkàn.” Joṣua bá súre fún wọn, lẹ́yìn náà, ó ní kí wọ́n pada lọ sí ilẹ̀ wọn, wọ́n sì pada lọ. Mose ti kọ́kọ́ fún ìdajì ẹ̀yà Manase ní ilẹ̀ ní Baṣani; Joṣua sì fún ìdajì yòókù ní ilẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ ti àwọn arakunrin wọn, ní ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani. Nígbà tí Joṣua rán wọn pada lọ sí ilé wọn, tí ó sì súre fún wọn, ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa kó ọpọlọpọ dúkìá pada lọ sí ilé yín, ati ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn, fadaka, wúrà, idẹ, irin, ati ọpọlọpọ aṣọ. Ẹ pín ninu ìkógun tí ẹ kó lọ́dọ̀ àwọn ọ̀tá yín fún àwọn arakunrin yín.” Nítorí náà àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase fi àwọn ọmọ Israẹli yòókù sílẹ̀ ní Ṣilo, tí ó wà ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n sì pada lọ sí ilẹ̀ Gileadi tí í ṣe ilẹ̀ tiwọn tí wọ́n pín fún wọn, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ láti ẹnu Mose. Nígbà tí wọ́n dé agbègbè odò Jọdani, tí ó wà ní ilẹ̀ Kenaani, àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi, ati ìdajì ẹ̀yà Manase tẹ́ pẹpẹ kan lẹ́bàá Jọdani, pẹpẹ náà tóbi pupọ. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ pé àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase ti tẹ́ pẹpẹ kan sí ìhà ibi tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Israẹli, ní agbègbè odò Jọdani, ní àtiwọ ilẹ̀ Kenaani, Nigba tí àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ èyí, gbogbo wọ́n bá péjọ sí Ṣilo láti lọ bá wọn jagun. Àwọn ọmọ Israẹli ranṣẹ sí ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase ní ilẹ̀ Gileadi, àwọn tí wọ́n rán ni Finehasi, ọmọ Eleasari, alufaa, ati àwọn olórí mẹ́wàá; wọ́n yan olórí kọ̀ọ̀kan láti inú ìdílé Israẹli kọ̀ọ̀kan, olukuluku wọn sì jẹ́ baálé ninu ìdílé wọn. Wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase ní ilẹ̀ Gileadi, wọ́n sọ fún wọn pé, “Gbogbo ìjọ eniyan Ọlọrun ní kí á bèèrè lọ́wọ́ yín pé, irú ìwà ọ̀dàlẹ̀ wo ni ẹ hù sí OLUWA Ọlọrun Israẹli yìí? Ẹ ti yára pada lẹ́yìn OLUWA, ẹ kò sì tẹ̀lé e mọ́, nítorí pé ẹ ti ṣe oríkunkun sí OLUWA nípa títẹ́ pẹpẹ fún ara yín. Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ tí a dá ní Peori, tí a kò tíì wẹ ara wa mọ́ kúrò ninu rẹ̀ kò tíì tó? Ṣebí nítorí ẹ̀ṣẹ̀ náà ni àjàkálẹ̀ àrùn fi bẹ́ sílẹ̀ ní ààrin ìjọ eniyan OLUWA? Kí ni ìbáà ṣẹlẹ̀, tí ẹ fi níláti yára yipada kúrò lọ́dọ̀ OLUWA bẹ́ẹ̀? Bẹ́ẹ̀ sì ni bí ẹ bá ṣe oríkunkun sí OLUWA lónìí, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni yóo bínú sí lọ́la. Bí ó bá jẹ́ pé ilẹ̀ yín kò mọ́ tó láti máa sin OLUWA níbẹ̀ ni, ẹ rékọjá sinu ilẹ̀ OLUWA, níbi tí àgọ́ rẹ̀ wà, ẹ wá gba ilẹ̀ láàrin wa. Ẹ ṣá má ti ṣe oríkunkun sí OLUWA, tabi kí ẹ sọ gbogbo wa di olóríkunkun nípa títẹ́ pẹpẹ mìíràn, yàtọ̀ sí pẹpẹ OLUWA Ọlọrun wa. Ṣebí ìwà ọ̀dàlẹ̀ báyìí náà ni Akani ọmọ Sera hù nígbà tí ó kọ̀, tí kò tẹ̀lé àṣẹ tí OLUWA pa nípa àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ OLUWA, ṣebí gbogbo ìjọ ọmọ Israẹli ni OLUWA bínú sí? Àbí òun nìkan ni ó ṣègbé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀?” Ni àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase bá dá àwọn olórí ẹ̀yà Israẹli lóhùn pé, “Ọlọrun Alágbára, Ọlọrun ni OLUWA! Ọlọrun Alágbára, Ọlọrun ni OLUWA, ó mọ ìdí tí a fi ṣe ohun tí a ṣe, a sì fẹ́ kí ẹ̀yin ọmọ Israẹli náà mọ̀ pẹlu. Tí ó bá jẹ́ pé oríkunkun ati ìwà ọ̀dàlẹ̀ ni a fẹ́ hù sí OLUWA ni a fi ṣe ohun tí a ṣe, ẹ má ṣàánú wa. Bí ó bá jẹ́ pé a tẹ́ pẹpẹ tí yóo mú wa kọ OLUWA sílẹ̀, tabi pé a tẹ́ pẹpẹ fún ẹbọ sísun, ati ẹbọ ohun jíjẹ, ati ẹbọ alaafia, kí OLUWA gbẹ̀san lára wa. Ká má rí i! Ohun tí ó mú wa ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ẹ̀rù ń bà wá pé, nígbà tí ó bá di ọjọ́ iwájú, àwọn ọmọ yín lè wí fún àwọn ọmọ wa pé, ‘Ọ̀rọ̀ OLUWA Ọlọrun Israẹli kò kàn yín. Nítorí OLUWA ti fi odò Jọdani ṣe ààlà láàrin àwa pẹlu yín, ẹ̀yin ẹ̀yà Reubẹni, ati ẹ̀yà Gadi, ẹ kò ní ìpín ninu nǹkan OLUWA.’ Àwọn ọmọ yín sì lè mú kí àwọn ọmọ wa má sin OLUWA mọ́. Nítorí náà, ni a ṣe wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á tẹ́ pẹpẹ kan,’ kì í ṣe fún ẹbọ sísun tabi ẹbọ mìíràn, ṣugbọn yóo wà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí, láàrin àwa pẹlu yín, ati àwọn ìran tí ń bọ̀ lẹ́yìn wa, pé àwa náà yóo máa sin OLUWA, a óo sì máa rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia níwájú rẹ̀. Kí àwọn ọmọ yín má baà wí fún àwọn ọmọ wa ní ọjọ́ iwájú pé, ‘Ẹ kò ní ìpín ninu nǹkan OLUWA.’ Èyí ni a fi ronú pé, bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ sọ bẹ́ẹ̀ sí wa, tabi sí àwọn ọmọ ọmọ wa ní ọjọ́ iwájú, a óo lè wí pé, ẹ wo irú pẹpẹ OLUWA tí àwọn baba ńlá wá tẹ́, kì í ṣe pé wọ́n rú ẹbọ sísun lórí rẹ̀, tabi ẹbọ mìíràn. Ẹ̀rí ni wọ́n fi ṣe láàrin àwa pẹlu yín. A kò jẹ́ ṣe oríkunkun sí OLUWA tabi kí á kọ̀ ọ́ sílẹ̀, kí a má sì sìn ín mọ́ kí á wá tẹ́ pẹpẹ mìíràn fún ẹbọ sísun tabi ẹbọ alaafia tabi ẹbọ mìíràn, yàtọ̀ sí pẹpẹ OLUWA Ọlọrun wa tí ó wà níwájú àgọ́ rẹ̀.” Nígbà tí Finehasi alufaa, ati àwọn olórí ìjọ eniyan, ati àwọn olórí ìdílé Israẹli tí wọ́n wà pẹlu wọn, gbọ́ ohun tí àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase wí, ọ̀rọ̀ náà dùn mọ́ wọn ninu. Finehasi ọmọ Eleasari, alufaa dá wọn lóhùn, ó ní, “Lónìí a mọ̀ pé OLUWA ń bẹ ní ààrin wa, nítorí pé ẹ kò hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí OLUWA, ẹ sì ti gba eniyan Israẹli lọ́wọ́ ìjìyà OLUWA.” Nígbà náà ni Finehasi ọmọ Eleasari, alufaa, ati àwọn olórí kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ati ẹ̀yà Gadi, ní ilẹ̀ Gileadi; wọ́n pada lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n sì jíṣẹ́ fún wọn. Iṣẹ́ tí wọ́n jẹ́ náà dùn mọ́ àwọn ọmọ Israẹli ninu, wọ́n sì fi ìyìn fún Ọlọrun; wọn kò sì ronú ati bá wọn jagun mọ́, tabi àtipa ilẹ̀ wọn run níbi tí wọ́n ń gbé. Àwọn ẹ̀yà Reubẹni ati ẹ̀yà Gadi bá pe pẹpẹ tí wọ́n tẹ́ ní, “Ẹ̀rí” nítorí wọ́n ní, “Pẹpẹ náà ni ẹ̀rí láàrin wa pé, OLUWA ni Ọlọrun.” Ó pẹ́ lẹ́yìn tí OLUWA ti fún Israẹli ní ìsinmi, tí kò sí ogun mọ́ láàrin àwọn ati gbogbo àwọn ọ̀tá tí ó yí wọn ká, Joṣua ti di àgbàlagbà ní àkókò yìí, ogbó sì ti dé sí i; ó bá pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, àwọn àgbààgbà, ati àwọn olórí, àwọn onídàájọ́, ati àwọn alákòóso, ó wí fún wọn pé, “Mo ti di àgbàlagbà, ogbó sì ti dé sí mi; ẹ̀yin náà ti rí ohun tí OLUWA Ọlọrun yín ti ṣe sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi nítorí yín, ati pé OLUWA Ọlọrun yín ni ó jà fun yín. Ẹ wò ó! Gbogbo ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí a kò tíì ṣẹgun, ati gbogbo àwọn tí a ti ṣẹgun ni mo ti pín fun yín gẹ́gẹ́ bí ogún yín, ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ láti odò Jọdani, títí dé Òkun Mẹditarenia ní apá ìwọ̀ oòrùn, OLUWA Ọlọrun yín yóo máa tì wọ́n sẹ́yìn fun yín, yóo máa lé wọn kúrò níwájú yín, ẹ óo sì gba ilẹ̀ wọn bí OLUWA Ọlọrun yín ti ṣèlérí fun yín. Nítorí náà, ẹ dúró ṣinṣin kí ẹ sì máa ṣe gbogbo nǹkan tí a kọ sinu ìwé òfin Mose. Ẹ kò gbọdọ̀ yẹ ẹsẹ̀ kúrò ninu wọn sí ọ̀tún tabi sí òsì, kí ẹ má baà darapọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ́kù láàrin yín, kí ẹ má baà máa bọ àwọn oriṣa wọn, tabi kí ẹ máa fi orúkọ wọn búra, tabi kí ẹ máa sìn wọ́n, tabi kí ẹ máa foríbalẹ̀ fún wọn. Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun yín ni kí ẹ súnmọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe títí di òní. Nítorí pé, OLUWA ti lé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n tóbi tí wọ́n sì ní agbára kúrò níwájú yín, kò sì tíì sí ẹni tí ó lè ṣẹgun yín títí di òní. Ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo ninu yín ni ó ń bá ẹgbẹrun eniyan jà, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín ni ó ń jà fun yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fun yín. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra, kí ẹ sì fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín. Nítorí pé, bí ẹ bá yipada, tí ẹ sì darapọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n ṣẹ́kù láàrin yín, tí ẹ̀ ń fẹ́ ọmọ lọ́wọ́ wọn, tí àwọn náà sì ń fẹ́ ọmọ lọ́wọ́ yín, ẹ mọ̀ dájú pé, OLUWA Ọlọrun yín kò ní lé àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi jáde kúrò fun yín mọ́; ṣugbọn wọn óo di ẹ̀bìtì ati tàkúté fun yín, OLUWA yóo sì fi wọ́n ṣe pàṣán tí yóo máa fi nà yín. Wọn óo dàbí ẹ̀gún, wọn óo máa gún yín lójú, títí tí ẹ óo fi parun patapata lórí ilẹ̀ dáradára tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín. “Nisinsinyii, ó tó àkókò fún mi láti kú, gbogbo yín ni ẹ sì mọ̀ dájúdájú ninu ọkàn yín pé, ninu gbogbo àwọn ohun rere tí OLUWA Ọlọrun yín ṣèlérí fun yín, kò sí èyí tí kò mú ṣẹ. Gbogbo wọn patapata ni wọ́n ṣẹ, ẹyọ kan kò yẹ̀ ninu wọn. Ṣugbọn bí OLUWA Ọlọrun yín ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ nípa àwọn nǹkan dáradára tí ó pinnu láti ṣe fun yín, bákan náà ni yóo mú kí gbogbo àwọn nǹkan burúkú tí ó ti ṣèlérí wá sórí yín, títí tí yóo fi run yín patapata lórí ilẹ̀ dáradára tí ó fun yín, tí ẹ kò bá pa majẹmu tí ó pa láṣẹ fun yín mọ́. Tí ẹ bá lọ bọ àwọn oriṣa, tí ẹ sì foríbalẹ̀ fún wọn, inú yóo bí OLUWA si yín, ẹ óo sì parun kíákíá lórí ilẹ̀ dáradára tí ó ti fun yín.” Joṣua pe gbogbo ẹ̀yà Israẹli jọ sí Ṣekemu, ó pe gbogbo àwọn àgbààgbà, àwọn olórí, àwọn onídàájọ́, ati àwọn alákòóso ilẹ̀ Israẹli; gbogbo wọn sì kó ara wọn jọ níwájú OLUWA. Ó wí fún gbogbo wọn pé, “Báyìí ni OLUWA Ọlọrun Israẹli wí, ‘Nígbà laelae, òkè odò Yufurate ni àwọn baba yín ń gbé: Tẹra, baba Abrahamu ati Nahori. Oriṣa ni wọ́n ń bọ nígbà náà. Láti òdìkejì odò náà ni mo ti mú Abrahamu baba yín, mo sìn ín la gbogbo ilẹ̀ Kenaani já; mo sì sọ arọmọdọmọ rẹ̀ di pupọ. Mo fún un ní Isaaki; mo sì fún Isaaki ni Jakọbu ati Esau. Mo fún Esau ní òkè Seiri bí ohun ìní tirẹ̀, ṣugbọn Jakọbu ati àwọn ọmọ rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Ijipti. Mo rán Mose ati Aaroni sí wọn ní ilẹ̀ Ijipti, mo fi àjàkálẹ̀ àrùn bá àwọn ará Ijipti jà, lẹ́yìn náà mo ko yín jáde. Mo kó àwọn baba yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. Nígbà tí ẹ dé etí òkun, àwọn ará Ijipti kó kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin, wọ́n sì lé àwọn baba yín títí dé etí Òkun Pupa. Nígbà tí àwọn baba yín ké pe OLUWA, OLUWA fi òkùnkùn sí ààrin ẹ̀yin ati àwọn ará Ijipti, ó sì mú kí òkun bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ẹ̀yin náà ṣá fi ojú yín rí ohun tí mo ṣe sí àwọn ará Ijipti. “ ‘Ẹ wà ninu aṣálẹ̀ fún ìgbà pípẹ́, lẹ́yìn náà mo ko yín wá sí ilẹ̀ àwọn ará Amori tí wọn ń gbé òdìkejì odò Jọdani. Wọ́n ba yín jà, mo sì fi wọ́n lé yín lọ́wọ́. Ẹ gba ilẹ̀ wọn, mo sì pa wọ́n run lójú yín. Lẹ́yìn náà, Balaki, ọmọ Sipori, ọba Moabu, dìde láti bá Israẹli jagun, ó ranṣẹ sí Balaamu, ọmọ Beori, láti wá fi yín gégùn-ún. Ṣugbọn n kò fetísí ọ̀rọ̀ Balaamu; nítorí náà ìre ni ó sú fun yín, mo sì gbà yín kúrò lọ́wọ́ rẹ̀. Ẹ gun òkè odò Jọdani wá sí Jẹriko, àwọn ará Jẹriko sì gbógun tì yín, ati àwọn ará Amori, àwọn ará Perisi, àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti, àwọn ará Girigaṣi, àwọn ará Hifi, ati àwọn ará Jebusi, mo sì fi wọ́n lé yín lọ́wọ́. Kì í ṣe idà tabi ọfà ni ẹ fi ṣẹgun àwọn ọba ará Amori mejeeji, agbọ́n ni mo rán ṣáájú yín tí ó sì lé wọn jáde fun yín. Mo fun yín ní ilẹ̀ tí ẹ kò ṣe làálàá fún, ati àwọn ìlú ńláńlá, tí ẹ kò tẹ̀ dó, ẹ sì ń gbé ibẹ̀. Ẹ̀ ń jẹ èso àjàrà ati ti igi olifi tí kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ gbìn.’ “Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù OLUWA, kí ẹ sì máa sìn ín tọkàntọkàn pẹlu òtítọ́ inú. Ẹ kó gbogbo oriṣa tí àwọn baba yín ń bọ ní òdìkejì odò ati ní Ijipti dànù, kí ẹ sì máa sin OLUWA. Bí kò bá wá wù yín láti máa sin OLUWA, ẹ yan ẹni tí ó bá wù yín láti máa sìn lónìí. Kì báà ṣe àwọn oriṣa tí àwọn baba yín ń bọ ní òdìkejì odò, tabi oriṣa àwọn ará Amori tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ wọn. Ṣugbọn ní tèmi ati ilé mi, OLUWA ni àwa óo máa sìn.” Nígbà náà ni àwọn eniyan náà dáhùn, wọ́n ní, “Kí á má rí i pé a kọ OLUWA sílẹ̀, a sì ń bọ oriṣa. Nítorí pé, OLUWA Ọlọrun wa ni ó kó àwa ati àwọn baba wa jáde ní oko ẹrú ilẹ̀ Ijipti, òun ni ó sì ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀n-ọn-nì lójú wa. Òun ni ó dá ẹ̀mí wa sí ní gbogbo ọ̀nà tí a tọ̀ láàrin gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí a là kọjá. OLUWA sì lé gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè náà kúrò níwájú wa ati àwọn ará Amori tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà tẹ́lẹ̀. Nítorí náà OLUWA ni a óo máa sìn nítorí pé òun ni Ọlọrun wa.” Ṣugbọn Joṣua dá àwọn eniyan náà lóhùn pé, “Ẹ kò lè sin OLUWA, nítorí pé Ọlọrun mímọ́ ni, Ọlọrun owú sì ni pẹlu, kò sì ní dárí àwọn àìṣedéédé ati ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín. Lẹ́yìn tí OLUWA bá ti ṣe yín lóore, bí ẹ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, tí ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí bọ àwọn oriṣa àjèjì, yóo yipada láti ṣe yín níbi, yóo sì pa yín run.” Àwọn eniyan náà dá Joṣua lóhùn pé, “Rárá o, OLUWA ni a óo máa sìn.” Joṣua bá wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí ara yín, pé OLUWA ni ẹ yàn láti máa sìn.” Wọ́n dáhùn pé, “Àwa ni ẹlẹ́rìí.” Lẹ́yìn náà, Joṣua sọ fún wọn pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ kó àwọn oriṣa àjèjì tí ó wà láàrin yín dànù, kí ẹ sì fi ọkàn sọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun Israẹli.” Àwọn eniyan náà dá Joṣua lóhùn pé, “OLUWA Ọlọrun wa ni a óo máa sìn, tirẹ̀ ni a óo sì máa gbọ́.” Joṣua bá dá majẹmu pẹlu àwọn eniyan náà ní ọjọ́ náà, ó sì ṣe òfin ati ìlànà fún wọn ní Ṣekemu. Ó kọ ọ̀rọ̀ náà sinu ìwé òfin Ọlọrun, ó gbé òkúta ńlá kan, ó sì fi gúnlẹ̀ lábẹ́ igi Oaku, ní ibi mímọ́ OLUWA, ó bá wí fún gbogbo wọn pé, “Ẹ wo òkúta yìí, òun ni yóo jẹ́ ẹlẹ́rìí láàrin wa, nítorí pé ó gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí OLUWA ti sọ fún wa, nítorí náà, òun ni yóo jẹ́ ẹlẹ́rìí fun yín, kí ẹ má baà hùwà aiṣododo sí Ọlọrun yín.” Joṣua bá pàṣẹ pé kí àwọn eniyan náà máa lọ, kí olukuluku pada sí orí ilẹ̀ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà tó yá, Joṣua ọmọ Nuni, iranṣẹ OLUWA kú nígbà tí ó di ẹni aadọfa (110) ọdún. Wọ́n bá sin ín sórí ilẹ̀ rẹ̀ ní Timnati Sera, tí ó wà ní agbègbè olókè Efuraimu, ní apá ìhà àríwá Gaaṣi. Àwọn ọmọ Israẹli sin OLUWA ní gbogbo àkókò tí Joṣua fi wà láàyè, ati ní àkókò àwọn àgbààgbà tí wọ́n ṣẹ́kù lẹ́yìn Joṣua, tí wọ́n mọ gbogbo ohun tí OLUWA ṣe fún Israẹli. Àwọn ọmọ Israẹli sin egungun Josẹfu tí wọ́n gbé wá láti ilẹ̀ Ijipti sí Ṣekemu, lórí ilẹ̀ tí Jakọbu fi ọgọrun-un fadaka rà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hamori, tíí ṣe baba Ṣekemu, ilẹ̀ náà sì di àjogúnbá fún arọmọdọmọ Josẹfu. Nígbà tí ó yá, Eleasari, ọmọ Aaroni kú; wọ́n sì sin ín sí Gibea, ìlú Finehasi, ọmọ rẹ̀, tí ó wà ní agbègbè olókè Efuraimu. Lẹ́yìn ikú Joṣua, àwọn ọmọ Israẹli bèèrè lọ́wọ́ OLUWA pé, “Ẹ̀yà wo ni kí ó kọ́kọ́ gbógun ti àwọn ará Kenaani?” OLUWA dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yà Juda ni kí ó kọ́ dojú kọ wọ́n, nítorí pé, mo ti fi ilẹ̀ náà lé wọn lọ́wọ́.” Àwọn ọmọ Juda bá tọ ẹ̀yà Simeoni, arakunrin wọn lọ, wọ́n ní, “Ẹ bá wa lọ síbi ilẹ̀ tí wọ́n pín fún wa, kí á lọ gbógun ti àwọn ará Kenaani. Nígbà tí ó bá yá, àwa náà yóo ba yín lọ síbi ilẹ̀ tí wọ́n pín fun yín.” Àwọn ẹ̀yà Simeoni bá tẹ̀lé wọn. Àwọn ọmọ Juda gbéra, wọ́n lọ gbógun ti àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Perisi. OLUWA fi wọ́n lé àwọn ọmọ Juda lọ́wọ́, wọ́n sì ṣẹgun ẹgbaarun (10,000) ninu wọn ní Beseki. Wọ́n bá Adonibeseki ní Beseki, wọ́n gbógun tì í, wọ́n sì ṣẹgun àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Perisi. Adonibeseki sá, ṣugbọn wọ́n lé e mú. Wọ́n gé àtàǹpàkò ọwọ́ ati ti ẹsẹ̀ rẹ̀ mejeeji. Adonibeseki bá dáhùn pé, “Aadọrin ọba tí mo ti gé àtàǹpàkò ọwọ́ ati ti ẹsẹ̀ wọn, ni wọ́n máa ń ṣa èérún oúnjẹ jẹ lábẹ́ tabili mi. Ẹ̀san ohun tí mo ṣe sí wọn ni Ọlọrun ń san fún mi yìí.” Wọ́n bá mú un wá sí Jerusalẹmu, ibẹ̀ ni ó sì kú sí. Àwọn ọmọ Juda gbógun ti ìlú Jerusalẹmu; wọ́n gbà á, wọ́n fi idà pa gbogbo àwọn tí wọn ń gbébẹ̀, wọ́n sì sun ún níná. Lẹ́yìn náà, wọ́n gbógun ti àwọn ará ilẹ̀ Kenaani tí wọ́n ń gbé orí òkè, ati ìhà gúsù tí à ń pè ní Nẹgẹbu, ati àwọn tí wọn ń gbé ẹsẹ̀ òkè náà pẹlu. Àwọn ọmọ Juda tún lọ gbógun ti àwọn ará Kenaani tí wọn ń gbé ìlú Heburoni, (Kiriati Araba ni orúkọ tí wọn ń pe Heburoni tẹ́lẹ̀); wọ́n ṣẹgun Ṣeṣai, Ahimani ati Talimai. Nígbà tí wọ́n kúrò níbẹ̀, wọ́n lọ gbógun ti ìlú Debiri. (Kiriati Seferi ni orúkọ tí wọ́n ń pe Debiri tẹ́lẹ̀.) Kalebu ní ẹnikẹ́ni tí ó bá gbógun ti ìlú Kiriati Seferi tí ó sì ṣẹgun rẹ̀, ni òun óo fi Akisa, ọmọbinrin òun fún kí ó fi ṣe aya. Otinieli, ọmọ Kenasi, àbúrò Kalebu, ṣẹgun ìlú náà, Kalebu bá fi Akisa, ọmọbinrin rẹ̀ fún un kí ó fi ṣe aya. Nígbà tí Akisa dé ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀, ọkọ rẹ̀ bẹ̀ ẹ́ pé kí ó tọrọ pápá ìdaran lọ́wọ́ baba rẹ̀. Ní ọjọ́ kan, Akisa lọ bá baba rẹ̀, bí ó ti ń sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni baba rẹ̀ bi í pé, “Kí lo fẹ́?” Ó bá dá baba rẹ̀ lóhùn pé, “Ẹ̀bùn kan ni mo fẹ́ tọrọ. Ṣé o mọ̀ pé ilẹ̀ aṣálẹ̀ ni o fún mi; nítorí náà, fún mi ní orísun omi pẹlu rẹ̀.” Kalebu bá fún un ní àwọn orísun omi tí ó wà ní òkè ati ní ìsàlẹ̀. Àwọn ọmọ ọmọ Keni, àna Mose, bá àwọn ọmọ Juda lọ láti Jẹriko, ìlú ọlọ́pẹ, sí inú aṣálẹ̀ Juda tí ó wà ní apá ìhà gúsù lẹ́bàá Aradi; wọ́n sì jọ ń gbé pọ̀ níbẹ̀. Àwọn ọmọ Juda bá àwọn ọmọ Simeoni, arakunrin wọn, lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kenaani tí wọ́n ń gbé Sefati. Wọ́n gbógun tì wọ́n, wọ́n run wọ́n patapata, wọ́n sì sọ ìlú náà ní Horima. Àwọn ọmọ Juda ṣẹgun ìlú Gasa ati àwọn ìlú tí ó wà ní agbègbè rẹ̀. Wọ́n ṣẹgun ìlú Aṣikeloni ati Ekironi ati àwọn ìlú tí ó wà ní agbègbè wọn. OLUWA wà pẹlu àwọn ọmọ Juda, ọwọ́ wọn tẹ àwọn ìlú olókè, ṣugbọn apá wọn kò ká àwọn tí ó ń gbé pẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí pé irin ni wọ́n fi ṣe kẹ̀kẹ́ ogun wọn. Wọ́n fún Kalebu ní Heburoni gẹ́gẹ́ bí Mose ti wí, Kalebu sì lé àwọn ọmọ Anaki mẹtẹẹta kúrò níbẹ̀. Ṣugbọn àwọn ọmọ Bẹnjamini kò lé àwọn ará Jebusi tí wọn ń gbé Jerusalẹmu jáde; láti ìgbà náà ni àwọn ará Jebusi ti ń bá àwọn ọmọ Bẹnjamini gbé ní Jerusalẹmu títí di òní olónìí. Àwọn ọmọ Josẹfu náà gbógun ti ìlú Bẹtẹli, OLUWA sì wà pẹlu wọn. Wọ́n rán àwọn amí láti lọ wo Bẹtẹli. (Lusi ni orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀.) Àwọn amí náà rí ọkunrin kan tí ń jáde bọ̀ láti inú ìlú náà, wọ́n wí fún un pé, “Jọ̀wọ́, fi ọ̀nà tí a óo gbà wọ ìlú yìí hàn wá, a óo sì ṣe ọ́ lóore.” Ọkunrin náà bá fi ọ̀nà tí wọn ń gbà wọ ìlú náà hàn wọ́n, wọ́n bá fi idà pa gbogbo àwọn ará ìlú náà, ṣugbọn wọ́n jẹ́ kí ọkunrin náà ati gbogbo ìdílé rẹ̀ jáde lọ. Ọkunrin náà lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Hiti, ó tẹ ìlú kan dó, ó sì sọ ọ́ ní Lusi. Orúkọ náà ni wọ́n ń pe ìlú náà títí di òní olónìí. Àwọn ọmọ Manase kò lé àwọn ará ìlú Beti Ṣeani ati àwọn ará Taanaki jáde, ati àwọn ará Dori, àwọn ará Ibileamu, àwọn ará Megido ati àwọn tí wọn ń gbé gbogbo àwọn ìletò tí ó wà ní àyíká àwọn ìlú náà; ṣugbọn àwọn ará Kenaani ṣì ń gbé ilẹ̀ náà. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli di alágbára sí i, wọ́n ń fi tipátipá kó àwọn ará Kenaani ṣiṣẹ́, ṣugbọn wọn kò lé wọn kúrò láàrin wọn patapata. Àwọn ọmọ Efuraimu kò lé àwọn ará Kenaani tí wọ́n ń gbé Geseri jáde, wọ́n jẹ́ kí wọ́n máa gbé ààrin wọn. Àwọn ọmọ Sebuluni kò lé àwọn tí wọ́n ń gbé ìlú Kitironi jáde, ati àwọn tí ó ń gbé Nahalali, ṣugbọn àwọn ará Kenaani ń bá wọn gbé, àwọn ọmọ Sebuluni sì ń fi tipátipá kó wọn ṣiṣẹ́. Àwọn ọmọ Aṣeri náà kò lé àwọn wọnyi jáde: àwọn ará Ako ati àwọn ará Sidoni, àwọn ará Ahilabu ati àwọn ará Akisibu, àwọn ará Heliba ati àwọn ará Afeki, ati àwọn ará Rehobu. Ṣugbọn àwọn ọmọ Aṣeri ń gbé ààrin àwọn ará Kenaani tí wọ́n bá ní ilẹ̀ náà, nítorí pé wọn kò lé wọn jáde. Àwọn ará Nafutali kò lé àwọn ará ìlú Beti Ṣemeṣi ati àwọn ará Betanati jáde, ṣugbọn wọ́n ń gbé ààrin àwọn tí wọ́n bá ni ilẹ̀ Kenaani. Ṣugbọn wọ́n ń fi tipátipá kó àwọn ará ìlú Beti Ṣemeṣi ati ti Betanati ṣiṣẹ́. Àwọn ará Amori ń lé àwọn ọmọ Dani sẹ́yìn sí àwọn agbègbè olókè, nítorí pé wọn kò fẹ́ gba àwọn ọmọ Dani láàyè rárá láti sọ̀kalẹ̀ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀. Àwọn ará Amori kọ̀, wọn kò jáde ní òkè Heresi, Aijaloni ati Ṣaalibimu, ṣugbọn àwọn ọmọ Josẹfu kò fi wọ́n lọ́rùn sílẹ̀ títí tí àwọn ọmọ Josẹfu fi bẹ̀rẹ̀ sí fi tipátipá kó wọn ṣiṣẹ́. Ààlà àwọn ará Amori bẹ̀rẹ̀ láti ẹsẹ̀ òkè Akirabimu, láti Sela lọ sókè. Angẹli OLUWA gbéra láti Giligali, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli ní Bokimu, ó sọ fún wọn pé, “Mo ko yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, wá sí ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba ńlá yín pé n óo fún wọn. Mo ní, ‘N kò ní yẹ majẹmu tí mo bá yín dá, ati pé, ẹ kò gbọdọ̀ bá èyíkéyìí ninu àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ yìí dá majẹmu kankan, ẹ sì gbọdọ̀ wó gbogbo pẹpẹ wọn lulẹ̀.’ Ṣugbọn ẹ kò mú àṣẹ tí mo pa fun yín ṣẹ. Irú kí ni ẹ dánwò yìí? Nítorí náà, n kò ní lé wọn jáde fun yín mọ́; ṣugbọn wọn yóo di ọ̀tá yín, àwọn oriṣa wọn yóo sì di tàkúté fún yín.” Nígbà tí Angẹli OLUWA sọ ọ̀rọ̀ yìí fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn. Ìdí nìyí tí wọ́n fi sọ orúkọ ibẹ̀ ní Bokimu, wọ́n sì rúbọ sí OLUWA níbẹ̀. Nígbà tí Joṣua tú àwọn ọmọ Israẹli ká, olukuluku wọn pada lọ sí orí ilẹ̀ wọn, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. Àwọn eniyan náà sin OLUWA ní gbogbo àkókò tí Joṣua ati àwọn àgbààgbà tí wọ́n kù lẹ́yìn rẹ̀ wà láàyè, àwọn tí wọ́n fi ojú rí àwọn iṣẹ́ ńlá tí OLUWA ṣe fún Israẹli. Joṣua, ọmọ Nuni, iranṣẹ OLUWA, ṣaláìsí nígbà tí ó di ẹni aadọfa (110) ọdún. Wọ́n sì sin ín sórí ilẹ̀ rẹ̀ ní Timnati Sera, ní agbègbè olókè ti Efuraimu ní ìhà àríwá òkè Gaaṣi. Gbogbo ìṣọ̀wọ́ àwọn tí wọ́n mọ OLUWA ati ohun tí ó ti ṣe fún Israẹli patapata ni wọ́n kú, àwọn ìran mìíràn sì dìde lẹ́yìn wọn, wọn kò mọ OLUWA, ati gbogbo ohun tí ó ti ṣe fún Israẹli. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, wọ́n ń bọ oriṣa Baali. Wọ́n kọ OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn tí ó kó wọn jáde láti ilẹ̀ Ijipti sílẹ̀, wọ́n ń bọ lára àwọn oriṣa àwọn tí wọ́n yí wọn ká, wọ́n ń foríbalẹ̀ fún wọn, wọ́n sì mú inú bí OLUWA. Wọ́n kọ OLUWA sílẹ̀, wọ́n ń bọ oriṣa Baali ati Aṣitarotu. Inú bí OLUWA sí àwọn ọmọ Israẹli, ó bá fi wọ́n lé àwọn jàǹdùkú ọlọ́ṣà kan lọ́wọ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jí wọn ní nǹkan kó. OLUWA tún fi wọ́n lé gbogbo àwọn ọ̀tá tí ó wà ní àyíká wọn lọ́wọ́, apá wọn kò sì ká àwọn ọ̀tá wọn mọ́. Nígbàkúùgbà tí wọ́n bá jáde lọ láti jagun, OLUWA á kẹ̀yìn sí wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti kìlọ̀ fún wọn tí ó sì búra fún wọn, ìdààmú a sì dé bá wọn. Lẹ́yìn náà, OLUWA á gbé àwọn adájọ́ kan dìde, àwọn adájọ́ náà á sì gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn jàǹdùkú ọlọ́ṣà tí ń kó wọn ní nǹkan. Sibẹsibẹ, wọn kì í gbọ́ ti àwọn aṣiwaju wọn. Wọn a máa sá lọ sọ́dọ̀ àwọn oriṣa káàkiri, wọn a sì máa bọ wọ́n. Láìpẹ́ láìjìnnà, wọ́n á yipada kúrò ní ọ̀nà tí àwọn baba wọn ń rìn. Àwọn baba wọn a máa pa òfin OLUWA mọ́, ṣugbọn ní tiwọn àwọn kì í pa á mọ́. Nígbàkúùgbà tí OLUWA bá gbé aṣiwaju kan dìde fún wọn, OLUWA a máa wà pẹlu aṣiwaju náà, a sì máa gbà wọ́n lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá wọn, ní àkókò aṣiwaju náà. Ìkérora àwọn ọmọ Israẹli a máa mú kí àánú wọn ṣe OLUWA, nígbà tí àwọn ọ̀tá wọn bá ń fìyà jẹ wọ́n, tí wọ́n sì ń ni wọ́n lára. Ṣugbọn bí aṣiwaju yìí bá ti kú, kíá, wọn a tún ti yipada, wọn a sì tún ti máa ṣe ohun tí ó burú ju ohun tí àwọn baba wọn ti ṣe lọ. Wọn a máa lọ sọ́dọ̀ àwọn oriṣa, wọ́n a máa bọ wọ́n, wọn a sì máa foríbalẹ̀ fún wọn. Wọn kì í sì í fi ìṣe wọn ati oríkunkun wọn sílẹ̀. Nítorí náà inú a bí OLUWA sí àwọn ọmọ Israẹli, a sì wí pé, “Àwọn eniyan wọnyi ti da majẹmu tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba wọn, wọn kò sì fetí sí òfin mi. Láti ìsinsìnyìí lọ n kò ní lé èyíkéyìí, ninu àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù kí Joṣua tó kú, jáde fún wọn. Àwọn ni n óo lò láti wò ó bí àwọn ọmọ Israẹli yóo máa tọ ọ̀nà tí mo là sílẹ̀, bí àwọn baba ńlá wọn ti ṣe.” Nítorí náà, OLUWA fi àwọn orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀ ninu ilẹ̀ náà, kò tètè lé wọn jáde bí kò ti fún Joṣua lágbára láti ṣẹgun wọn. OLUWA fi àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi sílẹ̀ láti fi dán Israẹli wò, pàápàá jùlọ, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọn kò tíì ní ìrírí ogun jíjà ní ilẹ̀ Kenaani. Kí àwọn ọmọ Israẹli lè mọ̀ nípa ogun jíjà, pataki jùlọ, ìṣọ̀wọ́ àwọn tí wọn kò mọ̀ nípa ogun jíjà tẹ́lẹ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA fi sílẹ̀ nìwọ̀nyí: àwọn olú-ìlú Filistini maraarun ati gbogbo ilẹ̀ Kenaani, àwọn ará Sidoni ati àwọn ará Hifi tí wọn ń gbé òkè Lẹbanoni, láti òkè Baali Herimoni títí dé ẹnubodè Hamati. Àwọn ni OLUWA fi dán àwọn ọmọ Israẹli wò, láti wò ó bóyá wọn óo mú àṣẹ tí òun pa fún àwọn baba wọn láti ọwọ́ Mose ṣẹ, tabi wọn kò ní mú un ṣẹ. Nítorí náà, àwọn ọmọ Israẹli ń gbé ààrin àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Hiti, àwọn ará Amori ati àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi, ati àwọn ará Jebusi. Àwọn ọmọ Israẹli ń fẹ́mọ lọ́wọ́ àwọn eniyan orílẹ̀-èdè náà, àwọn náà ń fi ọmọ fún wọn; àwọn ọmọ Israẹli sì ń bọ àwọn oriṣa wọn. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, wọ́n gbàgbé OLUWA Ọlọrun wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bọ oriṣa Baali ati Aṣerotu. Nítorí náà, inú bí OLUWA sí wọn, ó sì fi wọ́n lé Kuṣani Riṣataimu ọba Mesopotamia lọ́wọ́; wọn sì sìn ín fún ọdún mẹjọ. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n kígbe pé OLUWA, OLUWA gbé olùdáǹdè kan dìde fún wọn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Otinieli, ọmọ Kenasi, àbúrò Kalebu, òun ni ó gbà wọ́n kalẹ̀. Ẹ̀mí OLUWA bà lé e, ó sì ń ṣe ìdájọ́ àwọn ọmọ Israẹli. Ó jáde lọ sí ojú ogun, OLUWA sì fi Kuṣani Riṣataimu ọba Mesopotamia lé e lọ́wọ́, ó sì ṣẹgun rẹ̀. Nítorí náà, ilẹ̀ náà wà ní alaafia fún ogoji ọdún, lẹ́yìn náà, Otinieli ọmọ Kenasi ṣaláìsí. Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, OLUWA sì fún Egiloni, ọba ilẹ̀ Moabu, lágbára lórí wọn, nítorí pé wọ́n ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA. Egiloni yìí kó àwọn ará Amoni ati àwọn ará Amaleki sòdí, wọ́n lọ ṣẹgun àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì gba Jẹriko, ìlú ọlọ́pẹ, lọ́wọ́ wọn. Àwọn ọmọ Israẹli sin Egiloni, ọba ilẹ̀ Moabu, fún ọdún mejidinlogun. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n tún ké pe OLUWA, OLUWA gbé olùdáǹdè kan, ọlọ́wọ́ òsì, dìde, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ehudu, ọmọ Gera, ará Bẹnjamini. Ní àkókò kan àwọn ọmọ Israẹli fi ìṣákọ́lẹ̀ rán an sí Egiloni, ọba ilẹ̀ Moabu. Ehudu rọ idà olójú meji kan tí kò gùn ju igbọnwọ kan lọ, ó fi bọ inú àkọ̀, ó so ó mọ́ itan rẹ̀ ọ̀tún lábẹ́ aṣọ. Ó fi ìṣákọ́lẹ̀ náà jíṣẹ́ fún Egiloni, ọba ilẹ̀ Moabu. Egiloni yìí jẹ́ ẹni tí ó sanra rọ̀pọ̀tọ̀. Nígbà tí Ehudu fi ìṣákọ́lẹ̀ náà jíṣẹ́ tán, ó ní kí àwọn tí wọ́n rù ú máa pada lọ. Òun nìkan bá pada ní ibi òkúta tí wọ́n gbẹ́, tí ó wà lẹ́bàá Giligali, ó tọ ọba lọ, ó ní, “Kabiyesi, mo ní iṣẹ́ àṣírí kan tí mo fẹ́ jẹ́ fún ọ.” Ọba bá sọ fún gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé kí wọ́n jáde, gbogbo wọn sì jáde. Ehudu bá tọ̀ ọ́ lọ, níbi tí òun nìkan jókòó sí ninu yàrá tútù kan, lórí òrùlé ilé rẹ̀, ó wí fún un pé, “Ọlọ́run rán mi ní iṣẹ́ kan sí ọ,” ọba bá dìde níbi tí ó jókòó sí. Ehudu bá fi ọwọ́ òsì fa idà tí ó so mọ́ itan rẹ̀ ọ̀tún yọ, ó sì tì í bọ ọba Egiloni níkùn. Idà yìí wọlé tèèkùtèèkù, ọ̀rá sì padé mọ́ ọn, nítorí pé kò fa idà náà yọ kúrò ní ikùn ọba, ìfun ọba sì tú jáde. Ehudu bá jáde, ó sì fi kọ́kọ́rọ́ ti gbogbo ìlẹ̀kùn yàrá orí òrùlé náà. Lẹ́yìn tí ó ti sá lọ ni àwọn iranṣẹ ọba pada dé. Nígbà tí wọn rí i pé wọ́n ti fi kọ́kọ́rọ́ ti gbogbo ìlẹ̀kùn yàrá orí òrùlé náà, wọ́n rò ninu ara wọn pé, bóyá ọba wà ninu ilé ìgbọ̀nsẹ̀ tí ó wà ninu yàrá orí òrùlé náà ni. Wọ́n dúró títí tí agara fi dá wọn. Ṣugbọn nígbà tí ó kọ̀ tí kò ṣí ìlẹ̀kùn, wọ́n bá mú kọ́kọ́rọ́, wọ́n ṣí àwọn ìlẹ̀kùn; wọ́n bá bá òkú oluwa wọn nílẹ̀. Ní gbogbo ìgbà tí àwọn iranṣẹ wọnyi ń dúró pé kí ọba ṣílẹ̀kùn, Ehudu ti sá lọ, ó sì ti kọjá òkúta gbígbẹ́ tí ó wà lẹ́bàá Giligali, ó ti sá dé Seira. Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí fọn fèrè ní agbègbè olókè Efuraimu. Àwọn ọmọ Israẹli bá tẹ̀lé e lẹ́yìn láti agbègbè olókè, ó sì ṣiwaju wọn. Ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa tẹ̀lé mi, nítorí pé OLUWA ti fi àwọn ará Moabu, tíí ṣe ọ̀tá yín le yín lọ́wọ́.” Wọ́n bá ń tẹ̀lé e lọ, wọ́n gba ibi tí ó ṣe é fi ẹsẹ̀ là kọjá níbi odò Jọdani mọ́ àwọn ará Moabu lọ́wọ́, wọn kò sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kọjá. Wọ́n pa àwọn alágbára ati akikanju bí ẹgbaarun (10,000) ninu àwọn ará Moabu, kò sì sí ẹnìkan tí ó là ninu wọn. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli ṣe ṣẹgun wọn ní ọjọ́ náà, ilẹ̀ náà sì wà ní alaafia fún ọgọrin ọdún. Aṣiwaju tí ó tún dìde lẹ́yìn Ehudu ni Ṣamgari, ọmọ Anati, ẹni tí ó fi ọ̀pá tí wọ́n fi ń da mààlúù pa ẹgbẹta (600) ninu àwọn ará Filistia; òun náà gba Israẹli kalẹ̀. Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA lẹ́yìn ikú Ehudu. OLUWA bá fi wọ́n lé Jabini ọba Kenaani, tí ó jọba ní Hasori lọ́wọ́; Sisera, tí ń gbé Haroṣeti-ha-goimu ni olórí ogun rẹ̀. Àwọn ọmọ Israẹli bá tún ké pe OLUWA pé kí ó ran àwọn lọ́wọ́, nítorí pé ẹẹdẹgbẹrun (900) ni kẹ̀kẹ́ ogun Jabini tí wọ́n fi irin ṣe; ó sì ni wọ́n lára fún ogún ọdún. Wolii obinrin kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Debora aya Lapidotu, ni adájọ́ ní ilẹ̀ Israẹli nígbà náà. Lábẹ́ ọ̀pẹ kan, tí wọ́n sọ ní ọ̀pẹ Debora, tí ó wà láàrin Rama ati Bẹtẹli ní agbègbè olókè ti Efuraimu ní í máa ń jókòó sí, ibẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli tií máa ń lọ bá a fún ìdájọ́. Ó ranṣẹ pe Baraki, ọmọ Abinoamu, ní Kedeṣi, tí ó wà ní Nafutali, ó wí fún un pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ń pàṣẹ fún ọ pé kí o lọ kó àwọn eniyan rẹ̀ jọ ní òkè Tabori. Kó ẹgbaarun (10,000) eniyan ninu ẹ̀yà Nafutali ati Sebuluni jọ. N óo ti Sisera olórí ogun Jabini jáde láti pàdé rẹ lẹ́bàá odò Kiṣoni pẹlu àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ati àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, n óo sì fà á lé ọ lọ́wọ́.” Baraki bá dá a lóhùn pé, “Bí o óo bá bá mi lọ ni n óo lọ, bí o kò bá ní bá mi lọ, n kò ní lọ.” Debora dáhùn pé, “Láìṣe àní àní, n óo bá ọ lọ. Ṣugbọn ṣá o, ohun tí o fẹ́ ṣe yìí kò ní já sí ògo fún ọ, nítorí pé, OLUWA yóo fi Sisera lé obinrin kan lọ́wọ́.” Debora bá gbéra, ó bá Baraki lọ sí Kedeṣi. Baraki bá pe àwọn ọmọ Sebuluni ati Nafutali sí Kedeṣi; ẹgbaarun (10,000) ọkunrin ninu wọn ni wọ́n tẹ̀lé Baraki, Debora náà sì bá wọn lọ. Ní àkókò yìí, Heberi ará Keni ti kúrò ní ọ̀dọ̀ àwọn ará Keni yòókù tí wọ́n jẹ́ ìran Hobabu, àna Mose, ó sì pàgọ́ sí ẹ̀bá Kedeṣi lẹ́bàá igi oaku kan ní Saananimu. Nígbà tí Sisera gbọ́ pé Baraki ti lọ sí orí òkè Tabori, ó kó ẹẹdẹgbẹrun (900) kẹ̀kẹ́ ogun onírin rẹ̀ jọ, ó sì pe àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ láti Haroṣeti-ha-goimu títí dé odò Kiṣoni. Debora wí fún Baraki pé, “Dìde nítorí pé òní ni ọjọ́ tí OLUWA yóo fi Sisera lé ọ lọ́wọ́. Ṣebí OLUWA ni ó ń ṣáájú ogun rẹ lọ?” Baraki bá sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè Tabori pẹlu ẹgbaarun (10,000) ọmọ ogun lẹ́yìn rẹ̀. OLUWA mú ìdàrúdàpọ̀ bá Sisera ati gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ níwájú Baraki. Bí àwọn ọmọ ogun Baraki ti ń fi idà pa wọ́n, Sisera sọ̀kalẹ̀ ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ. Baraki lépa àwọn kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ọmọ ogun Sisera títí dé Haroṣeti-ha-goimu, wọ́n sì fi idà pa àwọn ọmọ ogun Sisera láìku ẹyọ ẹnìkan. Ṣugbọn Sisera sá lọ sí àgọ́ Jaeli, aya Heberi, ará Keni, nítorí pé alaafia wà ní ààrin Jabini, ọba Hasori, ati ìdílé Heberi ará Keni. Jaeli bá jáde lọ pàdé Sisera, ó wí fún un pé, “Máa bọ̀ níhìn-ín, oluwa mi. Yà wá sọ́dọ̀ mi, má bẹ̀rù.” Sisera bá yà sinu àgọ́ rẹ̀, ó sì fi aṣọ tí ó nípọn bò ó. Sisera bá bẹ̀ ẹ́ pé, “Jọ̀wọ́ òùngbẹ ń gbẹ mí, fún mi lómi mu.” Jaeli bá ṣí ìdérí ìgò tí wọ́n fi awọ ṣe, tí wọ́n da wàrà sí, ó fún un ní wàrà mu, ó sì tún da aṣọ bò ó. Sisera wí fún un pé, “Jọ̀wọ́ dúró ní ẹnu ọ̀nà àgọ́. Bí ẹnikẹ́ni bá wá, tí ó sì bi ọ́ léèrè pé, ‘Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni wà níbí?’ Wí fún olúwarẹ̀ pé, ‘Kò sí.’ ” Ó ti rẹ Sisera tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi sùn lọ fọnfọn. Jaeli bá mú òòlù kan, ati èèkàn àgọ́, ó yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ sí ibi tí Sisera sùn sí, ó kan èèkàn náà mọ́ ọn lẹ́bàá etí títí tí èèkàn náà fi wọlé, ó sì kú. Bí Baraki ti ń wá Sisera kiri, Jaeli lọ pàdé rẹ̀, ó wí fún un pé, “Máa bọ̀ níhìn-ín, n óo sì fi ẹni tí ò ń wá hàn ọ́.” Baraki bá bá a wọlé lọ, ó sì bá Sisera nílẹ̀ níbi tí ó kú sí, pẹlu èèkàn àgọ́ tí wọn gbá mọ́ ọn lẹ́bàá etí. Ní ọjọ́ náà ni Ọlọrun bá àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun Jabini, ọba àwọn ará Kenaani. Àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí kọlu Jabini, ọba Kenaani lemọ́lemọ́ títí wọ́n fi pa á run. Debora ati Baraki ọmọ Abinoamu bá kọrin ní ọjọ́ náà pé: Ẹ fi ìyìn fún OLUWA, nítorí pé, àwọn olórí ni wọ́n ṣiwaju ní Israẹli, àwọn eniyan sì fi tọkàntọkàn fa ara wọn kalẹ̀. Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọba; ẹ tẹ́tí sílẹ̀ ẹ̀yin ìjòyè; OLUWA ni n óo kọrin sí, n óo kọrin dídùn sí OLUWA, Ọlọrun Israẹli. OLUWA, nígbà tí o jáde lọ láti òkè Seiri, nígbà tí o jáde lọ láti agbègbè Edomu, ilẹ̀ mì tìtì, omi bẹ̀rẹ̀ sí bọ́, ọ̀wààrà òjò bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀. Àwọn òkè mì tìtì níwájú rẹ, OLUWA, àní, ní òkè Sinai níwájú OLUWA, Ọlọrun Israẹli. Ní ìgbà ayé Ṣamgari, ọmọ Anati, ati nígbà ayé Jaeli, ọ̀wọ́ èrò kò rin ilẹ̀ yìí mọ́, àwọn arìnrìnàjò sì ń gba ọ̀nà kọ̀rọ̀. Gbogbo ìlú dá wáí ní Israẹli, ó dá, gbogbo ìlú di àkọ̀tì, títí tí ìwọ Debora fi dìde, bí ìyá, ní Israẹli. Ní gbogbo ìgbà tí àwọn ọmọ Israẹli dá oriṣa titun, ogun bo gbogbo ẹnubodè. Ninu bí ọ̀kẹ́ meji (40,000) ọkunrin tí wọ́n wà ní Israẹli, ǹjẹ́ a rí ẹnikẹ́ni tí ó ní apata tabi ọ̀kọ̀? Ọkàn mi lọ sọ́dọ̀ àwọn balogun Israẹli, tí wọ́n fi tọkàntọkàn fa ara wọn kalẹ̀ láàrin àwọn eniyan. Ẹ fi ìyìn fún OLUWA. Ẹ máa fi ṣe ọ̀rọ̀ sọ, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ funfun, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń jókòó lórí ẹní olówó iyebíye, ati gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi ẹsẹ̀ rìn. Ẹ tẹ́tí sí ohùn àwọn akọrin lẹ́bàá odò, ibẹ̀ ni wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ́gun OLUWA, ọ̀rọ̀ ìṣẹ́gun àwọn eniyan rẹ̀ ní Israẹli. Àwọn eniyan OLUWA sì yan jáde láti ẹnubodè ìlú wọn. Gbéra ńlẹ̀! Gbéra ńlẹ̀! Debora! Gbéra ńlẹ̀! Gbéra ńlẹ̀, kí o dárin! Dìde, Baraki, máa kó àwọn tí o kó lógun lọ, ìwọ ọmọ Abinoamu! Àwọn akikanju yòókù bẹ̀rẹ̀ sí yan bọ̀, àwọn eniyan OLUWA náà sì ń wọ́ bọ̀, láti gbógun ti alágbára. Wọ́n gbéra láti Efuraimu lọ sí àfonífojì náà, wọ́n tẹ̀lé ọ, ìwọ Bẹnjamini pẹlu àwọn eniyan rẹ. Àwọn ọ̀gágun wá láti Makiri, àwọn olórí ogun sì wá láti Sebuluni. Àwọn ìjòyè Isakari náà bá Debora wá, àwọn ọmọ Isakari jẹ́ olóòótọ́ sí Baraki, wọ́n sì dà tẹ̀lé e lẹ́yìn lọ sí àfonífojì. Àwọn ẹ̀yà Reubẹni ṣiyèméjì, ìmọ̀ wọn kò ṣọ̀kan láti wá. Kí ló dé tí o fi dúró lẹ́yìn láàrin àwọn agbo aguntan? Tí o fi ń gbọ́ bí àwọn olùṣọ́-aguntan ti ń fọn fèrè fún àwọn aguntan wọn. Àwọn ẹ̀yà Reubẹni ṣiyèméjì, ìmọ̀ wọn kò ṣọ̀kan láti wá. Àwọn ará Gileadi dúró ní ìlà oòrùn odò Jọdani, kí ló dé tí ẹ̀yà Dani fi dúró ní ìdí ọkọ̀ ojú omi? Àwọn ẹ̀yà Aṣeri jókòó létí òkun, wọ́n wà ní ẹsẹ̀ odò. Àwọn ọmọ Sebuluni fi ẹ̀mí wọn wéwu dójú ikú, bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn ọmọ Nafutali, wọ́n fi ẹ̀mí ara wọn wéwu ninu pápá, lójú ogun. “Ní Taanaki lẹ́bàá odò Megido àwọn ọba wá, wọ́n jagun, wọ́n bá àwọn ọba Kenaani jagun, ṣugbọn wọn kò rí ìkógun fadaka kó. Láti ojú ọ̀run ni àwọn ìràwọ̀ ti ń jagun, àní láti ààyè wọn lójú ọ̀nà wọn, ni wọ́n ti bá Sisera jà. Odò Kiṣoni kó wọn lọ, odò Kiṣoni, tí ó kún àkúnya. Máa yan lọ, ìwọ ọkàn mi, máa fi agbára yan lọ. Àwọn ẹṣin sáré dé, pẹlu ariwo pátákò ẹsẹ̀ wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹsẹ̀ kilẹ̀.” Angẹli OLUWA ní, “Ìlú ègún ni ìlú Merosi, ẹni ègún burúkú sì ni àwọn olùgbé rẹ̀, nítorí pé wọ́n kọ̀, wọn kò wá ran OLUWA lọ́wọ́; wọn kò ran OLUWA lọ́wọ́ láti gbógun ti àwọn alágbára.” Ẹni ibukun jùlọ ni Jaeli láàrin àwọn obinrin, Jaeli, aya Heberi, ọmọ Keni, ẹni ibukun jùlọ láàrin àwọn obinrin tí ń gbé inú àgọ́. Omi ni Sisera bèèrè, wàrà ni Jaeli fún un, àwo tí wọ́n fi ń gbé oúnjẹ fún ọba ni ó fi gbé e fún un mu. Ó na ọwọ́ mú èèkàn àgọ́, ó na ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ó he òòlù àwọn alágbẹ̀dẹ, ó kan Sisera mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo; ó fọ́ ọ lórí, ó lù ú ní ẹ̀bá etí, ó sì fọ́ yángá-yángá. Sisera wó, ó ṣubú lulẹ̀, ó nà gbalaja lẹ́sẹ̀ Jaeli, ó wó lulẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀, ó ṣubú lulẹ̀. Ibi tí ó wó sí, náà ni ó sì kú sí. Ìyá Sisera ń yọjú láti ojú fèrèsé, ó bẹ̀rẹ̀ sí wo ọ̀nà láti ibi ihò fèrèsé. Ó ní, “Kí ló dé tí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ fi pẹ́ tóbẹ́ẹ̀ kí wọ́n tó dé? Kí ló dé tí ó fi pẹ́ tóbẹ́ẹ̀ kí á tó gbúròó ẹsẹ̀ àwọn ẹṣin tí wọ́n ń wọ́ kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀?” Àwọn ọlọ́gbọ́n jùlọ ninu àwọn obinrin tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ dá a lóhùn, òun náà sì ń wí fún ara rẹ̀ pé, “Ṣebí ìkógun ni wọ́n ń wá, tí wọ́n sì ń pín? Obinrin kan tabi meji fún ọkunrin kọ̀ọ̀kan, ìkógun àwọn aṣọ aláró fún Sisera, ìkógun àwọn aṣọ aláró tí wọ́n dárà sí lára, aṣọ ìborùn aláró meji tí wọ́n dárà sí lára fún èmi náà?” Bẹ́ẹ̀ ni kí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ ṣègbé, OLUWA; ṣugbọn bí oòrùn ti máa ń fi agbára rẹ̀ ràn, bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ máa tàn. Ilẹ̀ náà sì wà ní alaafia fún ogoji ọdún. Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣe nǹkan tí ó burú lójú OLUWA, OLUWA sì fi wọ́n lé àwọn ará Midiani lọ́wọ́ fún ọdún meje. Àwọn ará Midiani lágbára ju àwọn ọmọ Israẹli lọ tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli fi ṣe ibi tí wọn ń sápamọ́ sí lórí àwọn òkè, ninu ihò àpáta, ati ibi ààbò mìíràn ninu òkè. Nítorí pé, nígbàkúùgbà tí àwọn ọmọ Israẹli bá gbin ohun ọ̀gbìn wọn, àwọn ará Midiani ati àwọn ará Amaleki ati àwọn kan láti inú aṣálẹ̀ tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, a máa kó ara wọn jọ, wọn a lọ ṣígun bá àwọn ọmọ Israẹli. Wọn a gbógun tì wọ́n, wọn a sì ba gbogbo ohun ọ̀gbìn ilẹ̀ náà jẹ́ títí dé agbègbè Gasa. Wọn kì í fi oúnjẹ kankan sílẹ̀ rárá ní ilẹ̀ Israẹli, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í fi aguntan tabi mààlúù tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kankan sílẹ̀. Nítorí pé, nígbà tí wọ́n bá ń bọ̀, tilé-tilé ni wọ́n wá. Wọn á kó àwọn àgọ́ wọn ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn lọ́wọ́, wọn á sì bo àwọn ọmọ Israẹli bí eṣú. Àwọn ati ràkúnmí wọn kò níye, nítorí náà nígbà tí wọ́n bá dé, wọn á jẹ gbogbo ilẹ̀ náà ní àjẹrun. Àwọn ọmọ Israẹli di ẹni ilẹ̀ patapata, nítorí àwọn ará Midiani. Nítorí náà, wọ́n ké pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́. Nígbà tí wọ́n ké pe OLUWA, nítorí ìyọnu àwọn ará Midiani, OLUWA rán wolii kan sí wọn. Wolii náà bá sọ fún wọn pé, “OLUWA, Ọlọrun Israẹli ní, ‘Mo ko yín wá láti ilẹ̀ Ijipti, mo ko yín kúrò ní oko ẹrú. Mo gbà yín lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti, ati gbogbo àwọn tí wọn ń ni yín lára. Mo lé wọn jáde fún yín, mo sì fi ilẹ̀ wọn fun yín. Mo kìlọ̀ fún yín pé, èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, ati pé ẹ kò gbọdọ̀ bọ oriṣa àwọn ará Amori tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ wọn, ṣugbọn ẹ kò gbọ́ tèmi.’ ” Angẹli OLUWA kan wá, ó jókòó lábẹ́ igi Oaku tí ó wà ní Ofira, igi Oaku yìí jẹ́ ti Joaṣi, ará Abieseri. Bí Gideoni ọmọ Joaṣi, ti ń pa ọkà ní ibi tí wọ́n ti ń pọn ọtí, tí ó ń fi í pamọ́ fún àwọn ará Midiani, ni angẹli OLUWA náà yọ sí i, ó sì wí fún un pé, “OLUWA wà pẹlu rẹ, ìwọ akikanju ati alágbára ọkunrin.” Gideoni dá a lóhùn, ó ní “Jọ̀wọ́, oluwa mi, bí OLUWA bá wà pẹlu wa, kí ló dé tí gbogbo nǹkan wọnyi fi ń ṣẹlẹ̀ sí wa? Níbo sì ni gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu OLUWA wà, tí àwọn baba wa máa ń sọ fún wa nípa rẹ̀, pé, ‘Ṣebí OLUWA ni ó kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti?’ Ṣugbọn nisinsinyii OLUWA ti kọ̀ wá sílẹ̀, ó sì ti fi wá lé àwọn ará Midiani lọ́wọ́.” Ṣugbọn OLUWA yipada sí i, ó sì dá a lóhùn pé, “Lọ pẹlu agbára rẹ yìí, kí o sì gba Israẹli kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Midiani, ṣebí èmi ni mo rán ọ.” Gideoni dáhùn, ó ní, “Sọ fún mi OLUWA, báwo ni mo ṣe lè gba Israẹli sílẹ̀? Ìran mi ni ó rẹ̀yìn jùlọ ninu ẹ̀yà Manase, èmi ni mo sì kéré jù ní ìdílé wa.” OLUWA dá a lóhùn, ó ní, “N óo wà pẹlu rẹ, o óo sì run àwọn ará Midiani bí ẹni pé, ẹyọ ẹnìkan péré ni wọ́n.” Gideoni tún dáhùn, ó ní, “Bí inú rẹ bá yọ́ sí mi, fi àmì kan hàn mí pé ìwọ OLUWA ni ò ń bá mi sọ̀rọ̀. Jọ̀wọ́, má kúrò níhìn-ín títí tí n óo fi mú ẹ̀bùn mi dé, tí n óo sì gbé e kalẹ̀ níwájú rẹ.” Angẹli náà dá Gideoni lóhùn, ó ní, “N óo dúró títí tí o óo fi pada dé.” Gideoni bá wọlé lọ, ó tọ́jú ọmọ ewúrẹ́ kan, ó sì fi ìyẹ̀fun ìwọ̀n efa kan ṣe burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu. Ó kó ẹran tí ó sè sinu agbọ̀n kan, ó da omi ọbẹ̀ rẹ̀ sinu ìkòkò kan, ó gbé e tọ Angẹli OLUWA náà lọ ní abẹ́ igi Oaku, ó sì gbé wọn kalẹ̀ níwájú rẹ̀. Angẹli Ọlọrun náà wí fún un pé, “Da ẹran náà ati burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu náà sí orí àpáta yìí, kí o sì da omi ọbẹ̀ náà lé gbogbo rẹ̀ lórí.” Gideoni sì ṣe bẹ́ẹ̀. Angẹli OLUWA náà bá na ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi ṣóńṣó orí rẹ̀ kan ẹran ati burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu náà; iná bá ṣẹ́ lára àpáta, ó sì jó ẹran ati burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu náà. Angẹli OLUWA náà bá rá mọ́ ọn lójú. Nígbà náà ni Gideoni tó mọ̀ pé angẹli OLUWA ni, ó bá dáhùn pé, “Yéè! OLUWA Ọlọrun, mo gbé! Nítorí pé mo ti rí angẹli OLUWA lojukooju.” Ṣugbọn OLUWA dá a lóhùn pé, “Alaafia ni, má bẹ̀rù, o kò ní kú.” Gideoni bá tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún OLUWA, ó pe orúkọ rẹ̀ ní “OLUWA ni Alaafia.” Pẹpẹ náà wà ní Ofira ti ìdílé Abieseri títí di òní olónìí. Ní òru ọjọ́ náà, OLUWA sọ fún Gideoni pé, “Mú akọ mààlúù baba rẹ ati akọ mààlúù mìíràn tí ó jẹ́ ọlọ́dún meje, wó pẹpẹ oriṣa Baali baba rẹ lulẹ̀, kí o sì gé ère oriṣa Aṣera tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Kí o wá tẹ́ pẹpẹ kan fún èmi OLUWA Ọlọrun rẹ lórí òkítì ibi gegele náà. To àwọn òkúta rẹ̀ lérí ara wọn dáradára, lẹ́yìn náà mú akọ mààlúù keji kí o sì fi rú ẹbọ sísun. Igi ère oriṣa Aṣera tí o bá gé lulẹ̀ ni kí o fi ṣe igi ẹbọ sísun náà.” Gideoni mú mẹ́wàá ninu àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó sì ṣe bí OLUWA ti ní kí ó ṣe, ṣugbọn kò lè ṣe é lọ́sàn-án, nítorí ẹ̀rù àwọn ará ilé ati àwọn ará ìlú rẹ̀ ń bà á, nítorí náà lóru ni ó ṣe é. Nígbà tí àwọn ará ìlú náà jí ní òwúrọ̀ kutukutu, wọ́n rí i pé, wọ́n ti wó pẹpẹ oriṣa Baali lulẹ̀, wọ́n sì ti gé ère oriṣa Aṣera tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ati pé wọ́n ti fi mààlúù keji rúbọ lórí pẹpẹ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́. Wọ́n bá ń bi ara wọn léèrè pé, “Ta ló dán irú èyí wò?” Lẹ́yìn ìgbà tí wọn ti wádìí, wọ́n ní, “Gideoni ọmọ Joaṣi ni ó ṣe é.” Àwọn ará ìlú náà bá wí fún Joaṣi pé, “Mú ọmọ rẹ jáde kí á pa á, nítorí pé ó ti wó pẹpẹ oriṣa Baali, ó sì ti gé ère oriṣa Aṣera tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.” Ṣugbọn Joaṣi dá àwọn tí wọ́n dìde sí Gideoni lóhùn, ó ní, “Ṣé ẹ fẹ́ gbèjà oriṣa Baali ni, àbí ẹ fẹ́ dáàbò bò ó? Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbèjà rẹ̀, pípa ni a óo pa á kí ilẹ̀ tó mọ́. Bí ó bá jẹ́ pé ọlọrun ni Baali nítòótọ́, kí ó gbèjà ara rẹ̀, nítorí pẹpẹ rẹ̀ tí wọ́n wó lulẹ̀.” Nítorí náà, láti ọjọ́ náà lọ ni wọ́n ti ń pe Gideoni ní Jerubaali, ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, “Ẹ jẹ́ kí Baali bá a jà fúnra rẹ̀,” nítorí pé ó wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ̀. Nígbà náà ni gbogbo àwọn ará ilẹ̀ Midiani ati àwọn ará ilẹ̀ Amaleki ati àwọn ará ilẹ̀ tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn kó ara wọn jọ, wọ́n la odò Jọdani kọjá, wọ́n sì pàgọ́ wọn sí àfonífojì Jesireeli. Ṣugbọn Ẹ̀mí Ọlọrun bà lé Gideoni, Gideoni bá fọn fèrè ogun, àwọn ọmọ Abieseri bá pe ara wọn jáde wọ́n bá tẹ̀lé e. Ó ranṣẹ jákèjádò ilẹ̀ Manase, wọ́n pe ara wọn jáde, wọ́n sì tẹ̀lé e. Ó tún ranṣẹ bákan náà sí ẹ̀yà Aṣeri, ẹ̀yà Sebuluni, ati ẹ̀yà Nafutali, àwọn náà sì lọ pàdé rẹ̀. Gideoni wí fún Ọlọrun pé, “Bí ó bá jẹ́ pé èmi ni o fẹ́ lò láti gba Israẹli kalẹ̀, gẹ́gẹ́ bí o ti wí, n óo fi irun aguntan lélẹ̀ ní ibi ìpakà, bí ìrì bà sẹ̀ sórí irun yìí nìkan, tí gbogbo ilẹ̀ tí ó yí i ká bá gbẹ, nígbà náà ni n óo gbà pé nítòótọ́, èmi ni o fẹ́ lò láti gba Israẹli kalẹ̀, gẹ́gẹ́ bí o ti wí.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. Nígbà tí ó jí ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, tí ó sì fún irun aguntan náà, ìrì tí ó fún ní ara rẹ̀ kún abọ́ kan. Gideoni tún wí fún Ọlọrun pé, “Jọ̀wọ́, má jẹ́ kí inú bí ọ sí mi, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo yìí ni ó kù tí mo fẹ́ sọ̀rọ̀; jọ̀wọ́ jẹ́ kí n tún dán kinní kan wò pẹlu irun aguntan yìí lẹ́ẹ̀kan sí i, jẹ́ kí gbogbo irun yìí gbẹ ṣugbọn kí ìrì sẹ̀ sí gbogbo ilẹ̀, kí ó sì tutù.” Ọlọrun tún ṣe bẹ́ẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ náà, nítorí pé, orí irun yìí nìkan ṣoṣo ni ó gbẹ, ìrì sì sẹ̀ sí gbogbo ilẹ̀. Nígbà tí ó yá, Gideoni, tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Jerubaali, ati àwọn eniyan tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ kan, wọ́n lọ pàgọ́ sí ẹ̀gbẹ́ odò Harodu. Àgọ́ ti àwọn ará Midiani wà ní apá ìhà àríwá wọn ní àfonífojì lẹ́bàá òkè More. OLUWA wí fún Gideoni pé, “Àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ ti pọ̀jù fún mi, láti fi àwọn ará ilẹ̀ Midiani lé lọ́wọ́, kí àwọn ọmọ Israẹli má baà gbéraga pé agbára wọn ni wọ́n fi ṣẹgun, wọn kò sì ní fi ògo fún mi. Nítorí náà, kéde fún gbogbo wọn pé, kí ẹnikẹ́ni tí ẹ̀rù bá ń bà pada sí ilé.” Gideoni bá dán wọn wò lóòótọ́, ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaa (22,000) ọkunrin ninu wọn sì pada sí ilé. Àwọn tí wọ́n kù jẹ́ ẹgbaarun (10,000). OLUWA tún wí fún Gideoni pé, “Àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù yìí pọ̀jù sibẹsibẹ. Kó wọn lọ sí etí odò, n óo sì bá ọ dán wọn wò níbẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí mo bá wí fún ọ pé yóo lọ, òun ni yóo lọ, ẹnikẹ́ni tí mo bá sì wí fún ọ pé kò ní lọ, kò gbọdọ̀ lọ.” Gideoni bá kó àwọn eniyan náà lọ sí etí odò, OLUWA bá wí fún Gideoni pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ahọ́n lá omi gẹ́gẹ́ bí ajá, yọ ọ́ sọ́tọ̀ sí ẹ̀gbẹ́ kan, bákan náà ni kí o ṣe ẹnikẹ́ni tí ó bá kúnlẹ̀ kí ó tó mu omi. Àwọn tí wọ́n fi ọwọ́ bomi, tí wọ́n sì fi ahọ́n lá a bí ajá jẹ́ ọọdunrun (300), gbogbo àwọn yòókù ni wọ́n kúnlẹ̀ kí wọ́n tó mu omi. OLUWA bá wí fún Gideoni pé, “Àwọn ọọdunrun (300) tí wọ́n fi ahọ́n lá omi ni n óo lò láti gbà yín là, n óo sì fi àwọn ará Midiani lé ọ lọ́wọ́. Jẹ́ kí àwọn yòókù pada sí ilé wọn.” Gideoni bá gba oúnjẹ àwọn eniyan náà ati fèrè ogun wọn lọ́wọ́ wọn, ó sì sọ fún wọn pé kí wọ́n pada sí ilé, ṣugbọn ó dá àwọn ọọdunrun (300) náà dúró. Àgọ́ àwọn ọmọ ogun Midiani wà ní àfonífojì lápá ìsàlẹ̀ ibi tí wọ́n wà. OLUWA sọ fún un ní òru ọjọ́ kan náà pé, “Gbéra, lọ gbógun ti àgọ́ náà, nítorí pé mo ti fi lé ọ lọ́wọ́. Ṣugbọn bí ẹ̀rù bá ń bà ọ láti lọ, mú Pura iranṣẹ rẹ, kí ẹ jọ lọ sí ibi àgọ́ náà. O óo gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ, lẹ́yìn náà, o óo ní agbára láti lè gbógun ti àgọ́ náà.” Gideoni bà mú Pura, iranṣẹ rẹ̀, wọ́n jọ lọ sí ìpẹ̀kun ibi tí àwọn tí wọ́n di ihamọra ogun ninu àgọ́ wọn wà. Àwọn ará ilẹ̀ Midiani ati ti Amaleki ati àwọn ará ilẹ̀ tí ó wà ní ìlà oòrùn pọ̀ nílẹ̀ lọ bí eṣú àwọn ràkúnmí wọn kò níye, wọ́n pọ̀ bí iyanrìn etí òkun. Nígbà tí Gideoni dé ibẹ̀, ó gbọ́ tí ẹnìkan ń rọ́ àlá tí ó lá fún ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan pé, “Mo lá àlá kan, mo rí i tí àkàrà ọkà baali kan ré bọ́ sinu ibùdó àwọn ará Midiani. Bí ó ti bọ́ lu àgọ́ náà, ó wó o lulẹ̀, ó sì dojú rẹ̀ délẹ̀, àgọ́ náà sì tẹ́ sílẹ̀ pẹrẹsẹ.” Ẹnìkejì rẹ̀ dá a lóhùn, ó ní, “Èyí kì í ṣe ohun mìíràn, bíkòṣe idà Gideoni, ọmọ Joaṣi, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Israẹli. Ọlọrun ti fi Midiani ati gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ lé e lọ́wọ́.” Nígbà tí Gideoni gbọ́ bí ó ti rọ́ àlá yìí, ati ìtumọ̀ rẹ̀, ó yin OLUWA. Ó pada sí ibùdó Israẹli, ó ní, “Ẹ dìde, nítorí OLUWA ti fi àwọn ọmọ ogun Midiani le yín lọ́wọ́.” Ó pín àwọn ọọdunrun (300) náà sí ọ̀nà mẹta, ó fi fèrè ogun ati ìkòkò òfìfo tí wọn fi ògùṣọ̀ sí ninu lé ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn lọ́wọ́. Ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa wò mí, kí ẹ sì máa ṣe bí mo bá ti ń ṣe. Nígbà tí mo bá dé ìkangun àgọ́ náà, ẹ ṣe bí mo bá ti ṣe. Nígbà tí èmi ati àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ mi bá fọn fèrè, ẹ̀yin náà ẹ fọn fèrè tiyín ní gbogbo àyíká àgọ́ náà, ẹ óo sì pariwo pé, ‘Fún OLUWA, ati fún Gideoni.’ ” Gideoni ati ọgọrun-un eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá lọ sí ìkangun àgọ́ náà ní òru, nígbà tí àwọn olùṣọ́ mìíràn ṣẹ̀ṣẹ̀ gba ipò àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀. Wọ́n fọn fèrè, wọ́n sì fọ́ àwọn ìkòkò tí ó wà lọ́wọ́ wọn mọ́lẹ̀. Àwọn ẹgbẹ́ mẹtẹẹta fọn fèrè wọn, wọ́n sì fọ́ ìkòkò tì ó wà lọ́wọ́ wọn. Wọ́n fi iná ògùṣọ̀ wọn sí ọwọ́ òsì, wọ́n sì fi fèrè tí wọn ń fọn sí ọwọ́ ọ̀tún, wọ́n bá pariwo pé, “Idà kan fún OLUWA ati fún Gideoni.” Olukuluku wọn dúró sí ààyè wọn yípo àgọ́ náà, gbogbo àwọn ọmọ ogun Midiani bá bẹ̀rẹ̀ sí sá káàkiri, wọ́n ń kígbe, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ. Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Gideoni fọn ọọdunrun (300) fèrè wọn, Ọlọrun mú kí àwọn ọmọ ogun ọ̀tá wọn dojú ìjà kọ ara wọn, gbogbo wọn bá bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí apá Serera. Wọ́n sá títí dé Beti Ṣita, ati títí dé ààlà Abeli Mehola, lẹ́bàá Tabati. Àwọn ọmọ ogun Israẹli pe àwọn ọkunrin Israẹli jáde láti inú ẹ̀yà Nafutali, ati ti Aṣeri ati ti Manase, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn ará Midiani lọ. Gideoni rán àwọn oníṣẹ́ jákèjádò agbègbè olókè Efuraimu, ó ní, “Ẹ máa bọ̀ wá bá àwọn ará Midiani jagun, kí ẹ sì gba ojú odò lọ́wọ́ wọn títí dé Bẹtibara ati odò Jọdani.” Wọ́n pe gbogbo àwọn ọkunrin Efuraimu jáde, wọ́n sì gba gbogbo odò títí dé Bẹtibara ati odò Jọdani pẹlu. Wọ́n mú Orebu ati Seebu, àwọn ọmọ ọba Midiani mejeeji, wọ́n pa Orebu sí ibi òkúta Orebu, wọ́n sì pa Seebu níbi ìfúntí Seebu, bí wọ́n ti ń lé àwọn ará Midiani lọ. Wọ́n gé orí Orebu ati ti Seebu, wọ́n sì gbé wọn wá sí ọ̀dọ̀ Gideoni ní òdìkejì odò Jọdani. Àwọn ará Efuraimu bèèrè lọ́wọ́ Gideoni pé, “Irú kí ni o ṣe yìí, tí o kò pè wá, nígbà tí o lọ gbógun ti àwọn ara Midiani?” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sí i pẹlu ibinu. Ó dá wọn lóhùn, ó ní, “Kí ni mo ṣe lẹ́gbẹ̀ẹ́ èyí tí ẹ̀yin ṣe? Ohun tí ẹ̀yin ará Efuraimu ṣe, tí ẹ rò pé ohun kékeré ni yìí, ó ju gbogbo ohun tí àwọn ará Abieseri ṣe, tí ẹ kà kún nǹkan bàbàrà lọ. Ẹ̀yin ni Ọlọrun fi Orebu ati Seebu, àwọn ọmọ ọba Midiani mejeeji lé lọ́wọ́. Kí ni ohun tí mo ṣe lẹ́gbẹ̀ẹ́ èyí tí ẹ̀yin ṣe?” Nígbà tí wọ́n gbọ́ bí ó ṣe dá wọn lóhùn, inú wọ́n yọ́. Gideoni bá lọ sí odò Jọdani, ó sì kọjá odò náà sí òdìkejì rẹ̀, òun ati àwọn ọọdunrun (300) ọkunrin tí wọ́n tẹ̀lé e. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ wọ́n, sibẹsibẹ wọ́n ń lé àwọn ará Midiani lọ. Ó bẹ àwọn ará Sukotu, ó ní, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fún àwọn tí wọ́n tẹ̀lé mi ní oúnjẹ, nítorí pé ó ti rẹ̀ wọ́n, ati pé à ń lé Seba ati Salimuna, àwọn ọba Midiani mejeeji lọ ni.” Àwọn ìjòyè Sukotu dá a lóhùn, wọ́n ní, “Ṣé ọwọ́ rẹ ti tẹ Seba ati Salimuna ni, tí a óo fi fún ìwọ ati àwọn ọmọ ogun rẹ ní oúnjẹ?” Gideoni dá wọn lóhùn pé, “Kò burú, nígbà tí OLUWA bá fi Seba ati Salimuna lé mi lọ́wọ́, ẹ̀gún ọ̀gàn aṣálẹ̀ ati òṣùṣú ni n óo fi ya ẹran ara yín.” Ó kúrò níbẹ̀ lọ sí Penueli, ó sọ ohun kan náà fún wọn, ṣugbọn irú èsì tí àwọn ará Sukotu fún un ni àwọn ará Penueli náà fún un. Ó sọ fún àwọn ará Penueli pé, “Nígbà tí mo bá pada dé ní alaafia n óo wó ilé ìṣọ́ yìí.” Seba ati Salimuna wà ní ìlú Karikori pẹlu àwọn ọmọ ogun wọn yòókù, gbogbo àwọn ọmọ ogun ìlà oòrùn tí wọ́n ṣẹ́kù kò ju nǹkan bí ẹẹdẹgbaajọ (15,000) lọ, nítorí pé àwọn tí wọ́n ti kú ninu àwọn ọmọ ogun wọn tí wọ́n ń lo idà tó ọ̀kẹ́ mẹfa (120,000). Ọ̀nà èrò tí ó wà ní ìlà oòrùn Noba ati Jogibeha ni Gideoni gbà lọ, ó lọ jálu àwọn ọmọ ogun náà láì rò tẹ́lẹ̀. Seba ati Salimuna bá bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ, ṣugbọn Gideoni lé àwọn ọba Midiani mejeeji yìí títí tí ó fi mú wọn. Jìnnìjìnnì bá dàbo gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn. Ọ̀nà àtigun òkè Heresi ni Gideoni gbà nígbà tí ó ń ti ojú ogun pada bọ̀. Ọwọ́ rẹ̀ tẹ ọdọmọkunrin ará Sukotu kan, ó sì bèèrè orúkọ àwọn olórí ati àwọn àgbààgbà ìlú Sukotu lọ́wọ́ rẹ̀. Ọdọmọkunrin yìí sì kọ orúkọ wọn sílẹ̀, wọ́n jẹ́ ọkunrin mẹtadinlọgọrin. Ó bá wá sọ́dọ̀ àwọn ọkunrin Sukotu, ó ní, “Ẹ wo Seba ati Salimuna, àwọn ẹni tí ẹ tìtorí wọn pẹ̀gàn mi pé ọwọ́ mi kò tíì tẹ̀ wọ́n, tí ẹ kò sì fún àwọn ọmọ ogun mi tí àárẹ̀ mú ní oúnjẹ. Seba ati Salimuna náà nìyí o.” Ó kó gbogbo àwọn àgbààgbà ìlú náà, ó sì mú ẹ̀gún ọ̀gàn ati òṣùṣú, ó fi kọ́ wọn lọ́gbọ́n. Lẹ́yìn náà ó lọ sí Penueli, ó wó ilé ìṣọ́ wọn, ó sì pa àwọn ọkunrin ìlú náà. Lẹ́yìn náà, ó bi Seba ati Salimuna pé, “Níbo ni àwọn ọkunrin tí ẹ pa ní Tabori wà?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bí o ti rí gan-an ni ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn náà rí, gbogbo wọn dàbí ọmọ ọba.” Ó dáhùn, ó ní, “Arakunrin mi ni wọ́n, ìyá kan náà ni ó bí wa. Bí OLUWA ti wà láàyè, bí ó bá jẹ́ pé ẹ dá wọn sí ni, ǹ bá dá ẹ̀yin náà sí.” Ó bá pe Jeteri àkọ́bí rẹ̀, ó ní, “Dìde, kí o sì pa wọ́n,” ṣugbọn ọmọ náà kò fa idà rẹ̀ yọ nítorí pé ẹ̀rù ń bà á, nítorí ọmọde ni. Seba ati Salimuna bá dáhùn pé, “Ìwọ alára ni kí o dìde kí o pa wá? Ṣebí bí ọkunrin bá ṣe dàgbà sí ni yóo ṣe lágbára sí.” Gideoni bá dìde, ó pa Seba ati Salimuna, ó sì bọ́ ohun ọ̀ṣọ́ tí ó wà ní ọrùn ràkúnmí wọn. Lẹ́yìn èyí, àwọn ọmọ Israẹli wí fún Gideoni pé, “Máa jọba lórí wa, ìwọ ati ọmọ rẹ, ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ pẹlu, nítorí pé ìwọ ni o gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Midiani.” Gideoni dá wọn lóhùn, ó ní “N kò ní jọba lórí yín, bẹ́ẹ̀ ni ọmọ mi kò ní jọba lórí yín, OLUWA ni yóo máa jọba lórí yín.” Ṣugbọn ó rọ̀ wọ́n pé kí olukuluku wọn fún òun ní yẹtí tí ó wà ninu ìkógun rẹ̀, nítorí pé àwọn ará Midiani a máa lo yẹtí wúrà gẹ́gẹ́ bí àwọn ará ilẹ̀ Iṣimaeli yòókù. Wọ́n dá a lóhùn pé, “A óo fi tayọ̀tayọ̀ kó wọn fún ọ.” Wọ́n bá tẹ́ aṣọ kan sílẹ̀, olukuluku sì bẹ̀rẹ̀ sí ju yẹtí tí ó wà ninu ìkógun rẹ̀ sibẹ. Gbogbo ìwọ̀n yẹtí wúrà tí ó gbà jẹ́ ẹẹdẹgbẹsan (1,700) ṣekeli, láìka ohun ọ̀ṣọ́ ati aṣọ olówó iyebíye tí àwọn ọba Midiani wọ̀, ati àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ tí ó wà lọ́rùn àwọn ràkúnmí wọn. Gideoni bá fi wúrà yìí ṣe ère Efodu kan, ó gbé e sí ìlú rẹ̀ ní Ofira, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì bẹ̀rẹ̀ sí bọ ère oriṣa yìí, ó sì di tàkúté fún Gideoni ati ìdílé rẹ̀. Àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun àwọn ará Midiani, wọn kò sì lè gbérí mọ́; àwọn ọmọ Israẹli sì sinmi ogun jíjà fún ogoji ọdún, nígbà ayé Gideoni. Gideoni pada sí ilé rẹ̀, ó sì ń gbé ibẹ̀. Aadọrin ọmọ ni Gideoni bí, nítorí pé ó ní ọpọlọpọ aya. Obinrin rẹ̀ kan tí ń gbè Ṣekemu náà bí ọmọkunrin kan fún un, orúkọ ọmọ yìí ń jẹ́ Abimeleki. Gideoni ọmọ Joaṣi ṣaláìsí lẹ́yìn tí ó ti di arúgbó, wọ́n sin ín sinu ibojì Joaṣi, baba rẹ̀, ní Ofira àwọn ọmọ Abieseri. Bí Gideoni ti ṣaláìsí tán gẹ́rẹ́, àwọn ọmọ Israẹli tún bẹ̀rẹ̀ sí bọ oriṣa Baali, wọ́n sì sọ Baali-beriti di Ọlọrun wọn. Wọn kò ranti OLUWA Ọlọrun wọn tí ó gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá wọn ní gbogbo àyíká wọn. Wọn kò ṣe ìdílé Gideoni dáradára bí ó ti tọ́, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀san gbogbo nǹkan dáradára tí òun náà ti ṣe fún Israẹli. Abimeleki ọmọ Gideoni lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn eniyan ìyá rẹ̀ ní Ṣekemu, ó bá àwọn ati gbogbo ìdílé wọn sọ̀rọ̀, ó ní, kí wọn bèèrè lọ́wọ́ gbogbo àwọn ará ìlú Ṣekemu pé, èwo ni wọ́n fẹ́, tí wọ́n sì rò pé ó dára jù fún wọn, kí gbogbo aadọrin ọmọ Gideoni máa jọba lé wọn lórí ni, tabi kí ẹnìkan ṣoṣo jọba lórí wọn? Ó rán wọn létí pé, ìyekan wọn ni òun jẹ́. Àwọn eniyan ìyá rẹ̀ bá sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ní etígbọ̀ọ́ gbogbo àwọn ará ìlú Ṣekemu, wọn sì gbà láti tẹ̀lé Abimeleki tayọ̀tayọ̀. Wọ́n ní, “Arakunrin wa ni Abimeleki jẹ́.” Wọ́n mú aadọrin owó fadaka ninu ilé oriṣa Baali-beriti fún Abimeleki. Ó fi owó yìí kó àwọn oníjàgídíjàgan ati ìpátá kan jọ wọ́n sì ń tẹ̀lé e kiri. Ó bá lọ sí ilé baba rẹ̀ ní Ofira, ó pa gbogbo aadọrin àwọn arakunrin rẹ̀ lórí òkúta kan, àfi Jotamu àbíkẹ́yìn Gideoni nìkan ni ó ṣẹ́kù, nítorí pé òun sá pamọ́. Gbogbo àwọn ará ìlú Ṣekemu ati ti Bẹtimilo bá para pọ̀, wọ́n fi Abimeleki jọba níbi igi Oaku kan tí ó wà níbi ọ̀wọ̀n tí ó wà ní Ṣekemu. Nígbà tí Jotamu gbọ́, ó gun orí òkè Gerisimu lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pé, “Ẹ fi etí sílẹ̀, ẹ̀yin ọkunrin Ṣekemu, kí Ọlọrun lè gbọ́ tiyín. Ní àkókò kan, àwọn igi oko kó ara wọn jọ pé wọ́n fẹ́ ọba, wọ́n lọ sọ́dọ̀ igi Olifi, wọ́n wí fún un pé kí ó máa jọba lórí wọn. Ṣugbọn igi Olifi dá wọn lóhùn pé, ‘Ṣé kí n pa òróró ṣíṣe tì, tí àwọn oriṣa ati àwọn eniyan fi ń dá ara wọn lọ́lá tì, kí n má ṣe é mọ́, kí n wá jọba lórí ẹ̀yin igi?’ Àwọn igi bá lọ sí ọ̀dọ̀ igi ọ̀pọ̀tọ́, wọ́n sọ fún un pé kí ó wá jọba lórí àwọn. Ṣugbọn igi ọ̀pọ̀tọ́ dá wọn lóhùn pé, ‘Ṣé kí n pa èso mi dáradára tí ó ládùn tì, kí n wá jọba lórí yín?’ Àwọn igi bá tún lọ sọ́dọ̀ igi àjàrà, wọ́n wí fún un pé kí ó wá jọba lórí àwọn. Ṣugbọn igi àjàrà dá wọn lóhùn pé, ‘Ṣé kí ń pa ọtí mi, tí ń mú inú àwọn oriṣa ati àwọn eniyan dùn tì, kí n wá jọba lórí ẹ̀yin igi?’ Lẹ́yìn náà ni gbogbo àwọn igi sọ fún igi ẹ̀gún pé kí ó wá jọba lórí àwọn. Igi ẹ̀gún bá dá àwọn igi lóhùn pé, ‘Tí ó bá jẹ́ pé tinútinú yín ni ẹ fi fẹ́ kí n jọba yín, ẹ wá sábẹ́ ìbòòji mi, n óo sì dáàbò bò yín. Ṣugbọn bí bẹ́ẹ̀ bá kọ́, iná yóo yọ jáde láti ara ẹ̀gún mi, yóo sì jó igi kedari tí ó wà ní Lẹbanoni run.’ “Ǹjẹ́ òtítọ́ inú ati ọ̀nà ẹ̀tọ́ ni ẹ fi fi Abimeleki jọba? Ṣé ohun tí ẹ ṣe sí ìdílé Gideoni tọ́? Gbogbo sísìn tí ó sìn yín, ǹjẹ́ irú ohun tí ó yẹ kí ẹ fi san án fún un nìyí? Nítorí pé baba mi fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wéwu nígbà tí ó ń jà fun yín, ó sì gbà yín kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Midiani. Ṣugbọn lónìí, ẹ dìde sí ìdílé baba mi, ẹ sì pa aadọrin àwọn ọmọkunrin rẹ̀ lórí òkúta, ẹ wá fi Abimeleki, ọmọ iranṣẹbinrin rẹ̀ jọba lórí ìlú Ṣekemu, nítorí pé ó jẹ́ ìbátan yín. Nítorí náà, bí ó bá jẹ́ pé pẹlu òtítọ́ inú, ati ọ̀nà ẹ̀tọ́ ni ẹ fi ṣe ohun tí ẹ ṣe sí Gideoni ati ìdílé rẹ̀ lónìí, ẹ máa yọ̀ lórí Abimeleki kí òun náà sì máa yọ̀ lórí yín. Ṣugbọn bí bẹ́ẹ̀ kọ́, iná yóo jáde láti ara Abimeleki, yóo sì run gbogbo àwọn ará ìlú Ṣekemu ati Bẹtimilo. Bẹ́ẹ̀ ni iná yóo jáde láti ara àwọn ará ìlú Ṣekemu ati ti Bẹtimilo, yóo sì jó Abimeleki run.” Jotamu bá sá lọ sí Beeri, ó sì ń gbé ibẹ̀, nítorí ó bẹ̀rù Abimeleki arakunrin rẹ̀. Abimeleki jọba lórí Israẹli fún ọdún mẹta. Ọlọrun rán ẹ̀mí burúkú sí ààrin Abimeleki ati àwọn ara ìlú Ṣekemu. Àwọn ará ìlú Ṣekemu sì dìtẹ̀ mọ́ Abimeleki. Kí ẹ̀san pípa tí Abimeleki pa àwọn aadọrin ọmọ baba rẹ̀ ati ẹ̀jẹ̀ wọn lè wá sórí Abimeleki, ati àwọn ará ìlú Ṣekemu tí wọ́n kì í láyà láti pa wọ́n. Àwọn ará ìlú Ṣekemu bá rán àwọn kan ninu wọn, wọ́n lọ ba ní ibùba ní orí òkè de Abimeleki. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí dá gbogbo àwọn tí wọn ń kọjá lọ́nà; ni ìròyìn bá kan Abimeleki. Gaali ọmọ Ebedi ati àwọn arakunrin rẹ̀ kó lọ sí Ṣekemu, àwọn ará ìlú Ṣekemu sì gbẹ́kẹ̀lé e. Àwọn ará ìlú Ṣekemu lọ sinu oko wọn, wọ́n ká èso àjàrà, wọ́n fi pọn ọtí fún wọn. Wọ́n jọ ń ṣe àríyá, wọ́n jọ lọ sí ilé oriṣa wọn, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi Abimeleki ṣe ẹlẹ́yà. Gaali ọmọ Ebedi bá bèèrè pé, “Ta tilẹ̀ ni Abimeleki? Báwo sì ni àwa ará ìlú Ṣekemu ṣe jẹ́ sí i, tí a fi níláti máa sìn ín? Ṣebí àwọn ọmọ Hamori, baba Ṣekemu, ni Gideoni ati Sebulu, iranṣẹ rẹ̀ máa ń sìn? Kí ló dé tí àwa fi níláti máa sin Abimeleki? Ìbá ṣe pé ìkáwọ́ mi ni àwọn eniyan yìí wà, ǹ bá yọ Abimeleki kúrò lórí oyè. Ǹ bá sọ fún Abimeleki pé kí ó lọ wá kún àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kí ó jáde wá bá mi jà.” Nígbà tí Sebulu, olórí ìlú náà gbọ́ ohun tí Gaali, ọmọ Ebedi wí, inú bí i gidigidi. Ó ranṣẹ sí Abimeleki ní Aruma, ó ní, “Gaali, ọmọ Ebedi, ati àwọn arakunrin rẹ̀ ti dé sí Ṣekemu, wọn kò sì ní gbà fún ọ kí o wọ ibí mọ́. Nítorí náà, tí ó bá di òru, kí ìwọ ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ lọ ba níbùba. Bí ilẹ̀ bá ti mọ́, tí oòrùn sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ, gbéra, kí o sì gbógun ti ìlú náà. Nígbà tí Gaali ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá sì jáde sí ọ, mú wọn dáradára, kí o sì ṣe ẹ̀tọ́ fún wọn.” Abimeleki ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá gbéra ní òru, wọ́n lọ ba níbùba lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ṣekemu, ní ìsọ̀rí mẹrin. Gaali ọmọ Ebedi bá jáde, ó dúró ní ẹnu ọ̀nà bodè ìlú náà, Abimeleki ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ sì jáde níbi tí wọ́n ba sí. Nígbà tí Gaali rí wọn, ó sọ fún Sebulu pé, “Wò ó, àwọn eniyan kan ń sọ̀kalẹ̀ bọ̀ láti orí òkè.” Sebulu dá a lóhùn pé, “Òjìji òkè ni ò ń wò tí o ṣebí eniyan ni.” Gaali tún dáhùn, ó ní, “Tún wò ó, àwọn eniyan kan ń bọ̀ láti agbede meji ilẹ̀ náà, àwọn kan sì ń bọ̀ láti apá ibi igi Oaku àwọn tíí máa ń wo iṣẹ́.” Ṣugbọn Sebulu dá a lóhùn, pé, “Gbogbo ẹnu tí ò ń fọ́n pin, tabi kò pin? Ṣebí ìwọ ni o wí pé, ‘Kí ni Abimeleki jẹ́ tí a fi ń sìn ín.’ Àwọn tí ò ń gàn ni wọ́n dé yìí, yára jáde kí o lọ gbógun tì wọ́n.” Gaali bá kó àwọn ọkunrin Ṣekemu lẹ́yìn, wọ́n lọ gbógun ti Abimeleki. Abimeleki lé Gaali, Gaali sì sá fún un, ọpọlọpọ eniyan fara gbọgbẹ́ títí dé ẹnu ibodè ìlú. Abimeleki tún lọ ń gbé Aruma. Sebulu bá lé Gaali ati àwọn arakunrin rẹ̀ jáde kúrò ní ìlú, kò sì jẹ́ kí wọ́n gbé Ṣekemu mọ́. Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, Abimeleki gbọ́ pé àwọn ará Ṣekemu ń jáde lọ sinu pápá. Ó kó àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, ó pín wọn sí ìsọ̀rí mẹta, wọ́n sì ba níbùba ninu pápá. Bí ó ti rí i pé àwọn eniyan náà ń jáde bọ̀ láti inú ìlú, ó gbógun tì wọ́n, ó sì pa wọ́n. Abimeleki ati àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sáré, wọ́n lọ gba ẹnu ọ̀nà bodè ìlú. Àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun meji yòókù sáré sí gbogbo àwọn tí wọ́n wà ninu pápá, wọ́n pa wọ́n. Abimeleki gbógun ti ìlú náà ní gbogbo ọjọ́ náà, ó gbà á, ó sì pa àwọn eniyan inú rẹ̀; ó wó gbogbo ìlú náà palẹ̀, ó sì da iyọ̀ sí i. Nígbà tí gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbé ilé ìṣọ́ tí ó wà ní Ṣekemu gbọ́, wọ́n sá lọ sí ibi ààbò tí ó wà ní ilé Eli-beriti. Wọ́n sọ fún Abimeleki pé gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ilé ìṣọ́ tí ó wà ní Ṣekemu ti kó ara wọn jọ sí ibìkan. Abimeleki bá lọ sí òkè Salimoni, òun ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Ó mú àáké kan lọ́wọ́, ó fi gé ẹrù igi kan jọ, ó gbé e lé èjìká, ó sì sọ fún àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ pé, “Ẹ yára ṣe bí ẹ ti rí mi tí mo ṣe.” Olukuluku wọn náà bá gé ẹrù igi kọ̀ọ̀kan, wọ́n tẹ̀lé Abimeleki. Wọ́n to ẹrù igi wọn jọ sí ara ibi ààbò náà, wọn sọ iná sí i. Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ninu ilé ìṣọ́ Ṣekemu sì kú patapata. Wọ́n tó ẹgbẹrun (1,000) eniyan, atọkunrin, atobinrin. Abimeleki tún lọ sí Tebesi, ó gbógun tì í, ó sì gbà á. Ṣugbọn ilé ìṣọ́ kan tí ó lágbára wà ninu ìlú náà, gbogbo àwọn ará ìlú sá lọ sinu rẹ̀, atọkunrin, atobinrin. Wọ́n ti ara wọn mọ́ inú rẹ̀, wọ́n sì gun òkè ilé ìṣọ́ náà lọ. Nígbà tí Abimeleki dé ibi ilé ìṣọ́ náà, ó gbógun tì í. Ó súnmọ́ ẹnu ọ̀nà ilé ìṣọ́ náà láti dáná sun ún. Obinrin kan bá gbé ọmọ ọlọ kan, ó sọ ọ́ sílẹ̀, ọmọ ọlọ yìí bá Abimeleki lórí, ó sì fọ́ agbárí rẹ̀. Ó yára pe ọdọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀, ó wí fún un pé, “Fa idà rẹ yọ, kí o pa mí, kí àwọn eniyan má baà máa wí pé, ‘Obinrin kan ni ó pa á.’ ” Ọdọmọkunrin yìí bá gún un ní idà, ó sì kú. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli rí i pé Abimeleki ti kú, olukuluku gba ilé rẹ̀ lọ. Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun ṣe gbẹ̀san lára Abimeleki fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ baba rẹ̀, nítorí pé, ó pa aadọrin àwọn arakunrin rẹ̀. Ọlọrun sì mú kí gbogbo ìwà ibi àwọn ará Ṣekemu pada sórí wọn. Èpè tí Jotamu ọmọ Gideoni ṣẹ́ sì ṣẹ mọ́ wọn lára. Lẹ́yìn tí Abimeleki kú, Tola ọmọ Pua, ọmọ Dodo, láti inú ẹ̀yà Isakari ni ó dìde tí ó sì gba Israẹli kalẹ̀. Ìlú Ṣamiri tí ó wà ní agbègbè olókè ti Efuraimu ni ìlú rẹ̀. Ó jẹ́ aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli fún ọdún mẹtalelogun, nígbà tí ó ṣaláìsí wọ́n sin ín sí Ṣamiri. Jairi ará Gileadi ni ó di adájọ́ lẹ́yìn rẹ̀, ó jẹ́ aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli fún ọdún mejilelogun. Ó bí ọgbọ̀n ọmọkunrin, tí wọ́n ń gun ọgbọ̀n kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ọgbọ̀n ìlú ni wọ́n sì tẹ̀dó, tí wọn ń pe orúkọ wọn ní Hafoti Jairi títí di òní olónìí. Wọ́n wà ní ilẹ̀ Gileadi. Nígbà tí Jairi ṣaláìsí, wọ́n sin ín sí ilẹ̀ Kamoni. Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, wọ́n ń bọ àwọn oriṣa Baali, ati Aṣitarotu, oriṣa àwọn ará Siria ati àwọn ará Sidoni, ti àwọn ará Moabu ati àwọn ará Amoni, ati ti àwọn ará Filistia. Wọ́n kọ OLUWA sílẹ̀, wọn kò sìn ín mọ́. Inú tún bí OLUWA sí Israẹli ó sì fi wọ́n lé àwọn ará Filistia ati àwọn ará Amoni lọ́wọ́. Odidi ọdún mejidinlogun ni wọ́n fi ni àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ní òdìkejì odò Jọdani, ní Gileadi lára. Gileadi yìí wà ní ilẹ̀ àwọn ará Amoni. Àwọn ará Amoni sì tún kọjá sí òdìkejì odò Jọdani, wọ́n bá àwọn ẹ̀yà Juda, ẹ̀yà Bẹnjamini ati ẹ̀yà Manase jà, gbogbo Israẹli patapata ni wọ́n ń pọ́n lójú. Àwọn ọmọ Israẹli bá tún ké pe OLUWA, wọ́n ní, “A ti sẹ̀ sí ọ, nítorí pé a ti kọ ìwọ Ọlọrun wa sílẹ̀ a sì ń bọ àwọn oriṣa Baali.” OLUWA bá dá àwọn ọmọ Israẹli lóhùn, ó ní, “Ṣebí èmi ni mo gbà yín lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti ati àwọn ara Amori, ati àwọn ará Amoni ati àwọn ará Filistia. Nígbà tí àwọn ará Sidoni, àwọn ará Amaleki, ati àwọn ará Maoni ń pọn yín lójú; ẹ kígbe pè mí, mo sì gbà yín lọ́wọ́ wọn. Sibẹsibẹ ẹ tún kọ̀ mí sílẹ̀, ẹ sì ń bọ oriṣa. Nítorí náà n kò ní gbà yín là mọ́. Ẹ lọ bá àwọn oriṣa tí ẹ ti yàn, kí ẹ ké pè wọ́n, kí àwọn náà gbà yín ní ìgbà ìpọ́njú.” Àwọn ọmọ Israẹli bá dá OLUWA lóhùn pé, “A ti dẹ́ṣẹ̀, fi wá ṣe ohun tí ó bá wù ọ́. Jọ̀wọ́, ṣá ti gbà wá kalẹ̀ lónìí ná.” Wọ́n bá kó gbogbo àwọn àjèjì oriṣa tí ó wà lọ́wọ́ wọn dànù, wọ́n sì ń sin OLUWA. Inú bí OLUWA, nítorí ìpọ́njú àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ọmọ ogun Amoni múra ogun, wọ́n pàgọ́ sí Gileadi, àwọn ọmọ ogun Israẹli náà bá kó ara wọn jọ, wọ́n pàgọ́ tiwọn sí Misipa. Àwọn eniyan ati àwọn àgbààgbà Gileadi sì bèèrè lọ́wọ́ ara wọn pé, “Ta ni yóo kọ́kọ́ ko àwọn ọmọ ogun Amoni lójú?” Wọ́n ní, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ kò wọ́n lójú ni yóo jẹ́ olórí fún gbogbo àwa ará Gileadi.” Jẹfuta ará Gileadi jẹ́ akikanju jagunjagun, ṣugbọn ọmọ aṣẹ́wó ni; Gileadi ni baba rẹ̀. Ṣugbọn iyawo Gileadi gan-an bí àwọn ọmọkunrin mìíràn. Nígbà tí àwọn ọmọkunrin wọnyi dàgbà, wọ́n lé Jẹfuta jáde, wọ́n sọ fún un pé, “O kò lè bá wa pín ninu ogún baba wa, nítorí ọmọ obinrin mìíràn ni ọ́.” Jẹfuta bá sá jáde kúrò lọ́dọ̀ àwọn arakunrin rẹ̀, ó ń gbé ilẹ̀ Tobu. Àwọn aláìníláárí ati àwọn oníjàgídíjàgan kan bá kó ara wọn jọ sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bá ń bá a digun jalè káàkiri. Nígbà tí ó yá, àwọn ará Amoni gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli. Nígbà tí ogun yìí bẹ̀rẹ̀, àwọn àgbààgbà Gileadi lọ mú Jẹfuta wá láti ilẹ̀ Tobu. Wọ́n bẹ Jẹfuta, wọ́n ní, “A fẹ́ lọ gbógun ti àwọn ará Amoni, ìwọ ni a sì fẹ́ kí o jẹ́ balogun wa.” Ṣugbọn Jẹfuta dá wọn lóhùn pé, “Ṣebí ẹ̀yin ni ẹ kórìíra mi tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ fi lé mi jáde kúrò ní ilé baba mi? Kí ló dé tí ẹ fi wá sọ́dọ̀ mi nígbà tí ìyọnu dé ba yín?” Àwọn àgbààgbà Gileadi dá a lóhùn pé, “Ìyọnu tí ó dé bá wa náà ni ó mú kí á wá sọ́dọ̀ rẹ; kí o lè bá wa lọ, láti lọ gbógun ti àwọn ará Amoni. Ìwọ ni a fẹ́ kí o jẹ balogun gbogbo àwa ará Gileadi patapata.” Ó bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Bí ẹ bá mú mi pada wálé, láti bá àwọn ará Amoni jagun, bí OLUWA bá sì fi wọ́n lé mi lọ́wọ́ tí mo ṣẹgun wọn, ṣé ẹ gbà pé kí n máa ṣe olórí yín?” Àwọn àgbààgbà Gileadi dá a lóhùn pé, “OLUWA ni ẹlẹ́rìí láàrin àwa pẹlu rẹ pé, ohun tí o bá wí ni a óo ṣe.” Jẹfuta bá àwọn àgbààgbà Gileadi pada lọ, àwọn ará Gileadi sì fi jẹ balogun wọn. Ó lọ siwaju OLUWA ní Misipa, ó sì sọ àdéhùn tí ó bá àwọn àgbààgbà Gileadi ṣe. Lẹ́yìn náà, Jẹfuta ranṣẹ sí ọba àwọn ará Amoni pé, “Kí ni mo ṣe tí o fi gbógun ti ilẹ̀ mi.” Ọba Amoni bá rán àwọn oníṣẹ́ pada sí Jẹfuta pé, “Nígbà tí ẹ̀ ń bọ̀ láti ilẹ̀ Ijipti, ẹ gba ilẹ̀ mi, láti Anoni títí dé odò Jaboku, títí lọ kan odò Jọdani. Nítorí náà, ẹ yára dá ilẹ̀ náà pada ní alaafia.” Jẹfuta tún ranṣẹ pada sí ọba Amoni pé, “Gbọ́ ohun tí èmi Jẹfuta wí, Israẹli kò gba ilẹ̀ kankan lọ́wọ́ àwọn ará Moabu tabi lọ́wọ́ àwọn ará Amoni. Ṣugbọn nígbà tí wọn ń bọ̀ láti ilẹ̀ Ijipti, ààrin aṣálẹ̀ ni wọ́n gbà títí wọ́n fi dé Òkun Pupa, tí wọ́n sì fi dé Kadeṣi. Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti rán oníṣẹ́ sí ọba Edomu, wọ́n ní, ‘Ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí á gba ilẹ̀ yín kọjá.’ Ṣugbọn ọba Edomu kò gbà wọ́n láàyè rárá, bákan náà, wọ́n ranṣẹ sí ọba Moabu, òun náà kò fún wọn láàyè, àwọn ọmọ Israẹli bá jókòó sí Kadeṣi. Wọ́n bá gba aṣálẹ̀, wọ́n sì yípo lọ sí òdìkejì ilẹ̀ àwọn ará Edomu ati ti àwọn ará Moabu, títí tí wọ́n fi dé apá ìlà oòrùn ilẹ̀ àwọn ará Moabu. Wọ́n pàgọ́ wọn sí òdìkejì ilẹ̀ Anoni. Ṣugbọn wọn kò wọ inú ilẹ̀ àwọn ará Moabu, nítorí pé, ààlà ilẹ̀ Moabu ni Anoni wà. Israẹli bá tún rán oníṣẹ́ sí Sihoni, ọba àwọn ará Amori, tí ó wà ní ìlú Heṣiboni, wọ́n ní, ‘Jọ̀wọ́ jẹ́ kí á gba ilẹ̀ rẹ kọjá lọ sí agbègbè ilẹ̀ tiwa.’ Ṣugbọn Sihoni kò ní igbẹkẹle ninu àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọn kọjá láàrin ilẹ̀ rẹ̀. Ó bá kó gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ jọ, wọ́n pàgọ́ sí Jahasi, wọ́n sì gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli. OLUWA Ọlọrun Israẹli bà fi Sihoni ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ lé Israẹli lọ́wọ́, Israẹli ṣẹgun wọn, wọ́n sì gba ilẹ̀ àwọn ará Amori tí wọ́n ń gbé agbègbè náà. Wọ́n gba gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Amori láti Anoni títí dé odò Jaboku ati láti aṣálẹ̀ títí dé odò Jọdani. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun Israẹli ni ó gba ilẹ̀ náà lọ́wọ́ àwọn ará Amori fún àwọn ọmọ Israẹli. Ṣé ìwọ wá fẹ́ gbà á ni? Ṣé ohun tí Kemoṣi, oriṣa rẹ fún ọ, kò tó ọ ni? Gbogbo ohun tí OLUWA Ọlọrun wa ti gbà fún wa ni a óo fọwọ́ mú. Ṣé ìwọ sàn ju Balaki, ọmọ Sipori, ọba Moabu lọ ni? Ǹjẹ́ Balaki bá àwọn ọmọ Israẹli ṣe ìjàngbọ̀n kan tabi kí ó bá wọn jagun rí? Fún nǹkan bí ọọdunrun (300) ọdún tí Israẹli fi ń gbé Heṣiboni ati Aroeri, ati àwọn ìletò tí ó wà ní agbègbè wọn, ati àwọn ìlú ńláńlá tí ó wà ní etí odò Anoni, kí ló dé tí o kò fi gba ilẹ̀ rẹ láàrin àkókò náà? Nítorí náà, n kò ṣẹ̀ ọ́ rárá, ìwọ ni o ṣẹ̀ mí, nítorí pé o gbógun tì mí. Kí OLUWA onídàájọ́ dájọ́ lónìí láàrin àwọn ọmọ Israẹli ati Amoni.” Ṣugbọn ọba àwọn ará Amoni kò tilẹ̀ fetí sí iṣẹ́ tí Jẹfuta rán sí i rárá. Ẹ̀mí OLUWA bá bà lé Jẹfuta, ó bá kọjá láàrin Gileadi ati Manase, ó lọ sí Misipa ní ilẹ̀ Gileadi, láti ibẹ̀ ni ó ti lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Amoni. Jẹfuta bá jẹ́jẹ̀ẹ́ kan sí OLUWA, ó ní, “OLUWA, bí o bá ràn mí lọ́wọ́ tí mo bá ṣẹgun àwọn ara Amoni, nígbà tí mo bá ń pada bọ̀, lẹ́yìn tí mo bá ti ṣẹgun wọn tán, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ jáde láti wá pàdé mi láti inú ilé mi, yóo jẹ́ ti ìwọ OLUWA, n óo sì fi rú ẹbọ sísun sí ọ.” Jẹfuta bá rékọjá lọ sọ́dọ̀ àwọn ará Amoni láti bá wọn jagun, OLUWA sì fún un ní ìṣẹ́gun. Ó bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n láti Aroeri títí dé agbègbè Miniti tí ó fi wọ Abeli Keramimu. Àwọn ìlú tí ó run jẹ́ ogún. Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣẹgun àwọn ará Amoni. Jẹfuta bá pada sí ilẹ̀ rẹ̀ nì Misipa, bí ó ti ń wọ̀lú bọ̀, ọmọ rẹ̀ obinrin wá pàdé rẹ̀ pẹlu ìlù ati ijó, ọmọbinrin yìí sì ni ọmọ kan ṣoṣo tí ó bí. Bí ó ti rí i, ó fa aṣọ rẹ̀ ya ó ní, “Ha! Ọmọ mi, ìwọ ni o kó mi sinu ìbànújẹ́ yìí? Ó ṣe wá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tìrẹ ni yóo kó ìbànújẹ́ bá mi? Nítorí pé mo ti jẹ́jẹ̀ẹ́ níwájú OLUWA n kò sì gbọdọ̀ má mú un ṣẹ.” Ọmọbinrin náà dá baba rẹ̀ lóhùn pé, “Baba mi, bí o bá ti jẹ́jẹ̀ẹ́ kan níwájú OLUWA, ṣe sí mi gẹ́gẹ́ bí ẹ̀jẹ́ rẹ níwọ̀n ìgbà tí OLUWA ti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbẹ̀san lára àwọn ará Amoni, tí í ṣe ọ̀tá rẹ.” Ó bá bẹ baba rẹ̀, ó ní, “Kinní kan ni mo fẹ́ kí o ṣe fún mi, fi mí sílẹ̀ fún oṣù meji, kí èmi ati àwọn ẹlẹgbẹ́ mi lọ sí orí òkè kí á máa káàkiri, kí á sì máa sọkún, nítorí pé mo níláti kú láì mọ ọkunrin.” Baba rẹ̀ bá ní kí ó máa lọ fún oṣù meji. Òun ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ bá lọ sí orí òkè, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọkún, nítorí pé ó níláti kú, láì mọ ọkunrin. Lẹ́yìn oṣù meji, ó pada sọ́dọ̀ baba rẹ̀, baba rẹ̀ sì ṣe bí ó ti jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun yóo ṣe, ọmọbinrin náà kò mọ ọkunrin rí rárá. Ó sì di àṣà ní ilẹ̀ Israẹli, pé kí àwọn ọmọbinrin Israẹli máa lọ láti ṣọ̀fọ̀ ọmọbinrin Jẹfuta, ará Gileadi fún ọjọ́ mẹrin lọdọọdun. Àwọn ọmọ Efuraimu múra ogun, wọ́n ré odò Jọdani kọjá lọ sí Safoni. Wọ́n bi Jẹfuta léèrè pé, “Kí ló dé tí o fi rékọjá lọ sí òdìkejì láti bá àwọn ará Amoni jagun tí o kò sì pè wá pé kí á bá ọ lọ? Jíjó ni a óo jó ilé mọ́ ọ lórí.” Jẹfuta bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Nígbà kan tí ogun bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ará Amoni ati èmi pẹlu àwọn eniyan mi, tí mo ranṣẹ pè yín, ẹ kò gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ wọn. Mo sì ti mọ̀ pé ẹ kò tún ní gbà wá sílẹ̀, ni mo ṣe fi ẹ̀mí mi wéwu, tí mo sì kọjá sí òdìkejì lọ́dọ̀ àwọn ará Amoni; OLUWA sì fún mi ní ìṣẹ́gun lórí wọn. Kí ló wá dé tí ẹ fi dìde sí mi lónìí láti bá mi jà?” Jẹfuta bá kó gbogbo àwọn ọkunrin Gileadi jọ, wọ́n gbógun ti àwọn ará Efuraimu, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n, nítorí pé àwọn ará Efuraimu pe àwọn ará Gileadi ní ìsáǹsá Efuraimu, tí ó wà láàrin ẹ̀yà Efuraimu ati ẹ̀yà Manase. Àwọn ará Gileadi gba àwọn ipadò odò Jọdani lọ́wọ́ àwọn ará Efuraimu. Nígbà tí ìsáǹsá ará Efuraimu kan bá ń sá bọ̀, tí ó bá sọ fún àwọn ará Gileadi pé, “Ẹ jẹ́ kí n rékọjá.” Àwọn ará Gileadi á bi í pé, “Ǹjẹ́ ará Efuraimu ni ọ́?” Bí ó bá sọ pé, “Rárá,” wọn á ní kí ó pe, “Ṣiboleti.” Tí kò bá le pè é dáradára, tí ó bá wí pé, “Siboleti,” wọn á kì í mọ́lẹ̀, wọn á sì pa á létí odò Jọdani náà. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe pa ọ̀kẹ́ meji ati ẹgbaa (42,000) eniyan, ninu àwọn ará Efuraimu ní ọjọ́ náà. Jẹfuta ṣe aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli fún ọdún mẹfa. Nígbà tí ó ṣaláìsí, wọ́n sin ín sí Gileadi, ìlú rẹ̀. Lẹ́yìn Jẹfuta, Ibisani ará Bẹtilẹhẹmu ni aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli. Ó bí ọmọkunrin mejilelọgbọn, ó sì ní ọgbọ̀n ọmọbinrin. Ó fi àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin fọ́kọ láàrin àwọn tí wọn kì í ṣe ìbátan rẹ̀, ó sì fẹ́ ọgbọ̀n ọmọbinrin láti inú ẹ̀yà mìíràn wá fún àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin. Ó jẹ́ aṣiwaju ní Israẹli fún ọdún meje. Nígbà tí Ibisani ṣaláìsí, wọ́n sin ín sí Bẹtilẹhẹmu. Lẹ́yìn Ibisani, Eloni, láti inú ẹ̀yà Sebuluni, jẹ́ aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli fún ọdún mẹ́wàá. Nígbà tí Eloni ṣaláìsí, wọ́n sin ín sí Aijaloni ní ilẹ̀ Sebuluni. Lẹ́yìn rẹ̀, Abidoni, ọmọ Hileli, ará Piratoni, jẹ́ aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli. Ó ní ogoji ọmọkunrin ati ọgbọ̀n ọmọ ọmọ lọkunrin, tí wọn ń gun aadọrin kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Ó jẹ́ aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli fún ọdún mẹjọ. Lẹ́yìn náà, Abidoni ọmọ Hileli ará Piratoni ṣaláìsí, wọ́n sì sin ín sí Piratoni, ní ilẹ̀ Efuraimu, ní agbègbè olókè àwọn ará Amaleki. Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, OLUWA sì fi wọ́n lé àwọn ará Filistia lọ́wọ́. Wọ́n sin àwọn ará Filistia fún ogoji ọdún. Ọkunrin kan wà, ará Sora, láti inú ẹ̀yà Dani, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Manoa; àgàn ni iyawo rẹ̀, kò bímọ. Nígbà tí ó di ọjọ́ kan, angẹli OLUWA fi ara han iyawo Manoa yìí, ó wí fún un pé, “Lóòótọ́, àgàn ni ọ́, ṣugbọn o óo lóyún, o óo sì bí ọmọkunrin kan. Nítorí náà, ṣọ́ra, o kò gbọdọ̀ mu ọtí waini tabi ọtí líle, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó jẹ́ aláìmọ́. Nítorí pé, o óo lóyún, o óo sì bí ọmọkunrin kan. Abẹ kò gbọdọ̀ kan orí rẹ̀, nítorí pé, Nasiri Ọlọrun ni yóo jẹ́ láti ọjọ́ ìbí rẹ̀; òun ni yóo sì gba Israẹli sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Filistia.” Obinrin náà bá lọ sọ fún ọkọ rẹ̀, ó ní, “Eniyan Ọlọrun kan tọ̀ mí wá, ìrísí rẹ̀ jọ ìrísí angẹli Ọlọrun. Ó bani lẹ́rù gidigidi. N kò bèèrè ibi tí ó ti wá, kò sì sọ orúkọ ara rẹ̀ fún mi. Ṣugbọn ó wí fún mi pé, n óo lóyún, n óo sì bí ọmọkunrin kan. Ó ní n kò gbọdọ̀ mu ọtí waini, tabi ọtí líle. N kò sì gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó jẹ́ aláìmọ́; nítorí pé, Nasiri Ọlọrun ni ọmọ náà yóo jẹ́ láti ọjọ́ ìbí rẹ̀ títí yóo fi jáde láyé.” Manoa bá gbadura sí OLUWA, ó ní, “OLUWA, jọ̀wọ́ jẹ́ kí iranṣẹ rẹ tí o rán sí wa tún pada wá, kí ó wá kọ́ wa bí a óo ṣe máa tọ́jú ọmọkunrin tí a óo bí.” Ọlọrun gbọ́ adura Manoa, angẹli Ọlọrun náà tún pada tọ obinrin yìí wá níbi tí ó jókòó sí ninu oko; ṣugbọn Manoa, ọkọ rẹ̀, kò sí lọ́dọ̀ rẹ̀. Obinrin náà bá sáré lọ sọ fún ọkọ rẹ̀, ó ní, “Ẹni tí ó wá sọ́dọ̀ mi níjọ́sí tún ti fara hàn mí.” Manoa bá gbéra, ó bá tẹ̀lé iyawo rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ ọkunrin náà, ó bi í pé, “Ṣé ìwọ ni o bá obinrin yìí sọ̀rọ̀?” Ọkunrin náà dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.” Manoa tún bèèrè pé, “Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ, báwo ni ìgbé ayé ọmọ náà yóo rí? Irú kí ni yóo sì máa ṣe?” Angẹli OLUWA náà dá Manoa lóhùn, ó ní, “Gbogbo ohun tí mo sọ fún obinrin yìí ni kí o kíyèsí. Kò gbọdọ̀ fẹnu kan ohunkohun tí ó bá jáde láti inú èso àjàrà, kò gbọdọ̀ mu waini tabi ọtí líle tabi kí ó jẹ ohunkohun tí ó jẹ́ aláìmọ́. Gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún un ni kí ó ṣe.” Manoa dá angẹli OLUWA náà lóhùn, ó ní, “Jọ̀wọ́, dúró díẹ̀ kí á se ọmọ ewúrẹ́ kan fún ọ.” Angẹli OLUWA náà dá Manoa lóhùn, ó ní, “Bí o bá dá mi dúró, n kò ní jẹ ninu oúnjẹ rẹ, ṣugbọn tí o bá fẹ́ tọ́jú ohun tí o fẹ́ fi rú ẹbọ sísun, OLUWA ni kí o rú u sí.” Manoa kò mọ̀ pé angẹli OLUWA ni. Manoa bá bèèrè lọ́wọ́ angẹli OLUWA náà, ó ní, “Kí ni orúkọ rẹ kí á lè dá ọ lọ́lá nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ.” Angẹli OLUWA náà dáhùn pé, “Kí ló dé tí o fi ń bèèrè orúkọ mi nígbà tí ó jẹ́ pé ìyanu ni?” Manoa bá mú ọmọ ewúrẹ́ náà, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ, ó fi wọ́n rúbọ lórí òkúta kan sí OLUWA tí ń ṣe iṣẹ́ ìyanu. Nígbà tí ọwọ́ iná ẹbọ náà bẹ̀rẹ̀ sí yọ sókè láti orí pẹpẹ, angẹli OLUWA náà bẹ̀rẹ̀ sí gòkè lọ ninu ọwọ́ iná orí pẹpẹ náà, bí Manoa ati iyawo rẹ̀ ti ń wò ó. Wọ́n bá dojú wọn bolẹ̀. Angẹli OLUWA náà kò tún fara han Manoa ati iyawo rẹ̀ mọ́. Manoa wá mọ̀ nígbà náà pé, angẹli OLUWA ni. Manoa bá sọ fún iyawo rẹ̀ pé, “Dájúdájú, a óo kú, nítorí pé a ti rí Ọlọrun.” Ṣugbọn iyawo rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Bí ó bá ṣe pé OLUWA fẹ́ pa wá ni, kò ní gba ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ tí a rú sí i lọ́wọ́ wa, bẹ́ẹ̀ ni kò ní fi nǹkan wọnyi hàn wá, tabi kí ó sọ wọ́n fún wa.” Nígbà tí ó yá, obinrin náà bí ọmọkunrin kan, ó sì sọ ọ́ ní Samsoni. Ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí dàgbà, OLUWA sì bukun un. Ẹ̀mí OLUWA sì bẹ̀rẹ̀ sí lò ó ní Mahanedani, tí ó wà láàrin Sora ati Eṣitaolu. Samsoni lọ sí Timna, ó rí ọ̀kan ninu àwọn ọmọbinrin ará Filistia níbẹ̀. Ó pada wálé wá sọ fún baba ati ìyá rẹ̀, ó ní, “Mo rí ọ̀kan ninu àwọn ọmọbinrin ará Filistia ní Timna, ó wù mí, ẹ jọ̀wọ́, ẹ fẹ́ ẹ fún mi.” Baba ati ìyá rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Ṣé kò sí obinrin mọ́ ninu gbogbo àwọn ìbátan rẹ tabi láàrin gbogbo àwọn eniyan wa ni o fi níláti lọ fẹ́ aya láàrin àwọn ará Filistia aláìkọlà ni?” Samsoni bá bẹ baba rẹ̀, ó ní, “Ẹ ṣá fẹ́ ẹ fún mi nítorí ó wù mí pupọ.” Ṣugbọn baba ati ìyá rẹ̀ kò mọ̀ pé ọ̀rọ̀ náà ní ọwọ́ OLUWA ninu, nítorí pé OLUWA ti ń wá ọ̀nà láti mú àwọn ará Filistia nítorí pé, àwọn ni wọ́n ń mú àwọn ọmọ Israẹli sìn ní àkókò yìí. Samsoni bá baba ati ìyá rẹ̀ lọ sí Timna ní ọjọ́ kan. Bí ó ti dé ibi ọgbà àjàrà àwọn ará Timna kan báyìí, ni ọ̀dọ́ kinniun kan bá bú mọ́ ọn. Ẹ̀mí OLUWA bà lé e, ó sì fún un ní agbára ńlá, ó bá fa kinniun náà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ bí ìgbà tí eniyan ya ọmọ ewúrẹ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni kò mú ohunkohun lọ́wọ́. Ṣugbọn kò sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún baba tabi ìyá rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó lọ bá ọmọbinrin náà sọ̀rọ̀. Ọmọbinrin náà wù ú gidigidi. Kò pẹ́ pupọ lẹ́yìn náà, ni ó pada lọ láti lọ mú iyawo rẹ̀. Bí ó ti ń lọ, ó yà wo òkú kinniun tí ó pa, ó bá ọ̀wọ́ oyin ati afárá oyin lára rẹ̀. Ó bá yọ́ ninu afárá oyin náà sí ọwọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí lá a bí ó ti ń lọ. Nígbà tí ó bá baba ati ìyá rẹ̀, ó fún wọn lá ninu rẹ̀; ṣugbọn kò sọ fún wọn pé ara òkú kinniun ni òun ti rẹ́ afárá oyin náà. Baba rẹ̀ bá lọ sí ọ̀dọ̀ obinrin náà. Samsoni se àsè ńlá kan níbẹ̀, nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọdọmọkunrin máa ń ṣe nígbà náà. Nígbà tí àwọn eniyan náà rí i, wọ́n mú ọgbọ̀n ninu àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ wá láti wà pẹlu rẹ̀. Samsoni bá sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí n pa àlọ́ kan fun yín, bí ẹ bá lè túmọ̀ àlọ́ náà láàrin ọjọ́ meje tí a ó fi se àsè igbeyawo yìí, n óo fun yín ní ọgbọ̀n ẹ̀wù funfun ati ọgbọ̀n aṣọ àríyá. Ṣugbọn bí ẹ kò bá lè túmọ̀ àlọ́ náà, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yóo fún mi ní ẹ̀wù funfun kọ̀ọ̀kan ati aṣọ àríyá kọ̀ọ̀kan.” Wọ́n bá dáhùn pé, “Pa àlọ́ rẹ kí á gbọ́.” Ó bá pa àlọ́ náà fún wọn, ó ní, “Láti inú ọ̀jẹun ni nǹkan jíjẹ tií wá, láti inú alágbára sì ni nǹkan dídùn tií wá.” Wọn kò sì lè túmọ̀ àlọ́ rẹ̀ fún ọjọ́ mẹta. Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹrin, wọ́n wá bẹ iyawo Samsoni pé, “Tan ọkọ rẹ kí ó sọ ìtumọ̀ àlọ́ náà fún wa, láì ṣe bẹ́ẹ̀, a óo sun ìwọ ati ilé baba rẹ níná. Àbí pípè tí o pè wá wá sí ibí yìí, o fẹ́ sọ wá di aláìní ni?” Iyawo Samsoni bá bẹ̀rẹ̀ sì sọkún níwájú rẹ̀, ó ní, “O kò fẹ́ràn mi rárá, irọ́ ni ò ń pa fún mi. O kórìíra mi; nítorí pé o pa àlọ́ fún àwọn ará ìlú mi, o kò sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi.” Samsoni bá dá a lóhùn pé, “Ohun tí n kò sọ fún baba tabi ìyá mi, n óo ti ṣe wá sọ fún ọ?” Ni iyawo rẹ̀ bá tún bẹ̀rẹ̀ sí sọkún títí gbogbo ọjọ́ mejeeje tí wọ́n fi se àsè náà. Ṣugbọn nígbà tí ó di ọjọ́ keje, Samsoni sọ fún un, nítorí pé ó fún un lọ́rùn gidigidi. Obinrin náà bá lọ sọ ìtumọ̀ àlọ́ náà fún àwọn ará ìlú rẹ̀. Nígbà tí ó di ọjọ́ keje, kí ó tó di pé oòrùn wọ̀, àwọn ará ìlú rẹ̀ náà wá sọ ìtumọ̀ àlọ́ Samsoni wí pé, “Kí ló dùn ju oyin lọ; kí ló lágbára ju kinniun lọ?” Ó ní, “Bí kò bá jẹ́ pé mààlúù mi ni ẹ fi tulẹ̀, ẹ kì bá tí lè túmọ̀ àlọ́ mi.” Ẹ̀mí OLUWA bá bà lé e tagbára tagbára, ó lọ sí Aṣikeloni, ó sì pa ọgbọ̀n ninu àwọn ọkunrin ìlú náà, ó kó ìkógun wọn, ó sì fún àwọn tí wọ́n túmọ̀ àlọ́ rẹ̀ ní aṣọ àríyá wọn; ó bá pada lọ sí ilé baba rẹ̀ pẹlu ibinu. Wọ́n bá fi iyawo rẹ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ ninu àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní àkókò igbeyawo. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ní àkókò ìkórè ọkà, Samsoni mú ọmọ ewúrẹ́ kan, ó lọ bẹ iyawo rẹ̀ wò. Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó ní, “Mo fẹ́ wọlé lọ bá iyawo mi ninu yàrá.” Ṣugbọn baba iyawo rẹ̀ kò jẹ́ kí ó wọlé lọ bá a. Baba iyawo rẹ̀ wí fún un pé, “Mo rò pé lóòótọ́ ni o kórìíra iyawo rẹ, nítorí náà, mo ti fi fún ẹni tí ó jẹ́ ọrẹ rẹ tímọ́tímọ́, ninu àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ. Ṣé ìwọ náà rí i pé àbúrò rẹ̀ lẹ́wà jù ú lọ, jọ̀wọ́ fẹ́ ẹ dípò rẹ̀.” Samsoni dáhùn pé, “Bí mo bá ṣe àwọn ará Filistia ní ibi ní àkókò yìí, n kò ní jẹ̀bi wọn.” Samsoni bá lọ, ó mú ọọdunrun (300) kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ láàyè, ó wá ìtùfù, ó sì so àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà ní ìrù pọ̀ ní meji meji, ó fi ìtùfù sí ààrin ìrù wọn. Ó ṣáná sí àwọn ìtùfù náà, ó sì tú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà sílẹ̀ ninu oko ọkà àwọn ará Filistia. Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ yìí bá tan iná ran gbogbo ìtí ọkà ati àwọn ọkà tí ó wà ní òòró ati gbogbo ọgbà olifi wọn; gbogbo wọn sì jóná ráúráú. Àwọn ará Filistia bá bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè pé, “Ta ni ó dán irú èyí wò?” Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Samsoni, ọkọ ọmọ ará Timna ni; nítorí pé àna rẹ̀ fi iyawo rẹ̀ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀.” Àwọn ará Filistia bá lọ dáná sun iyawo náà ati baba rẹ̀. Samsoni bá sọ fún wọn pé, “Bí ó bá jẹ́ pé bí ẹ óo ti ṣe nìyí n óo gbẹ̀san lára yín, lẹ́yìn náà, n óo fi yín sílẹ̀.” Samsoni pa ọpọlọpọ ninu wọn. Ó kúrò níbẹ̀, ó sì lọ ń gbé inú ihò àpáta kan tí ó wà ní Etamu. Àwọn ará Filistia bá kógun wá sí Juda, wọ́n sì kọlu ìlú Lehi. Àwọn ọkunrin Juda bá bèèrè pé, “Kí ló dé tí ẹ fi gbógun tì wá?” Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Samsoni ni a wá mú; ohun tí ó ṣe sí wa ni àwa náà fẹ́ ṣe sí i.” Ẹgbẹẹdogun (3,000) ọkunrin Juda lọ bá Samsoni ní ibi ihò àpáta tí ó wà ní Etamu, wọ́n sọ fún un pé, “Ṣé o kò mọ̀ pé àwọn ará Filistia ni wọ́n ń ṣe àkóso wa ni? Irú kí ni o ṣe sí wa yìí?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Oró tí wọ́n dá mi ni mo dá wọn.” Wọ́n dá a lóhùn pé, “A wá láti dì ọ́ tọwọ́ tẹsẹ̀ kí á sì gbé ọ lọ fún àwọn ará Filistia ni.” Samsoni dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ búra fún mi pé ẹ̀yin tìkara yín kò ní pa mí.” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Rárá, àwa óo dì ọ́, a óo sì gbé ọ lé wọn lọ́wọ́ ni, a kò ní pa ọ́ rárá.” Wọ́n bá mú okùn titun meji, wọ́n fi dì í, wọ́n sì gbé e jáde láti inú ihò àpáta náà. Nígbà tí ó dé Lehi, àwọn Filistia wá hó pàdé rẹ̀. Ẹ̀mí OLUWA bà lé Samsoni tagbára tagbára, okùn tí wọ́n fi dè é sì já bí ìgbà tí iná ràn mọ́ fọ́nrán òwú. Gbogbo ìdè tí wọ́n fi dè é já kúrò ní ọwọ́ rẹ̀. Ó rí egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ pa, ó mú un, ó sì fi pa ẹgbẹrun ninu àwọn ará Filistia. Samsoni bá dáhùn pé, “Páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni mo fi pa wọ́n jọ bí òkítì, Egungun ẹ̀rẹ̀kẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni mo fi pa ẹgbẹrun eniyan.” Lẹ́yìn tí ó wí báyìí tán, ó ju egungun ẹ̀rẹ̀kẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà sílẹ̀, wọ́n sì sọ ibẹ̀ ní Ramati Lehi. Òùngbẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí gbẹ ẹ́ gidigidi, ó sì gbadura sí OLUWA, ó ní, “Ìwọ ni o ran èmi iranṣẹ rẹ lọ́wọ́ láti ṣẹgun lónìí, ṣugbọn ṣé òùngbẹ ni yóo wá gbẹ mí pa, tí n óo fi bọ́ sí ọwọ́ àwọn aláìkọlà wọnyi?” Ọlọrun bá la ibi ọ̀gbun kan tí ó wà ní Lehi, omi sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde láti inú ọ̀gbun náà. Lẹ́yìn tí ó mu omi tán, ojú rẹ̀ wálẹ̀, nítorí náà, wọ́n sọ ibẹ̀ ní Enhakore. Enhakore yìí sì wà ní Lehi títí di òní olónìí. Samsoni ṣe aṣiwaju ní Israẹli ní àkókò àwọn Filistini fún ogún ọdún. Ní ọjọ́ kan, Samsoni lọ sí ìlú Gasa, ó rí obinrin aṣẹ́wó kan níbẹ̀, ó bá wọlé tọ̀ ọ́ lọ. Àwọn kan bá lọ sọ fún àwọn ará Gasa pé Samsoni wà níbẹ̀. Wọ́n yí ilé náà po, wọ́n sì ba dè é níbi ẹnu ọ̀nà bodè ìlú ní gbogbo òru ọjọ́ náà. Wọ́n dákẹ́ rọ́rọ́, wọ́n ní, “Ẹ jẹ́ kí á dúró títí di ìdájí kí á tó pa á.” Ṣugbọn Samsoni sùn títí di ọ̀gànjọ́ òru. Ní òru náà, ó gbéra, ó gbá ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà bodè ìlú náà mú ati àwọn òpó rẹ̀ mejeeji, ó sì fà á tu pẹlu irin ìdábùú rẹ̀, ó gbé wọn lé èjìká, ó sì rù wọ́n lọ sí orí òkè kan tí ó wà ní iwájú Heburoni. Lẹ́yìn èyí, Samsoni rí obinrin kan tí ó wù ú ní àfonífojì Soreki, ó sì fẹ́ ẹ. Delila ni orúkọ obinrin náà. Àwọn ọba Filistia wá sọ́dọ̀ obinrin yìí, wọ́n ní, “Tan ọkọ rẹ, kí o sì mọ àṣírí agbára rẹ̀, ati ọ̀nà tí a fi lè kápá rẹ̀; kí á lè dì í lókùn kí á sì ṣẹgun rẹ̀. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wa yóo sì fún ọ ní ẹẹdẹgbẹfa (1,100) owó fadaka.” Delila bá pe Samsoni, ó ní, “Jọ̀wọ́, sọ àṣírí agbára rẹ fún mi, ati bí eniyan ṣe lè so ọ́ lókùn kí eniyan sì kápá rẹ.” Samsoni dá a lóhùn pé, “Bí wọ́n bá fi awọ tí wọ́n fi ń ṣe ọrun, tí kò tíì gbẹ meje dè mí, yóo rẹ̀ mí, n óo sì dàbí àwọn ọkunrin yòókù.” Àwọn ọba Filistini bá kó awọ tí wọ́n fi ń ṣe ọrun, titun, meje, tí kò tíì gbẹ, fún Delila, ó sì fi so Samsoni. Ó ti fi àwọn eniyan pamọ́ sinu yàrá inú. Ó bá pe Samsoni, ó ní, “Samsoni àwọn ará Filistia dé.” Ṣugbọn Samsoni já awọ ọrun náà bí ìgbà tí iná já fọ́nrán òwú lásán. Wọn kò sì mọ àṣírí agbára rẹ̀. Delila tún wí fún Samsoni pé, “Ò ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà, o sì ń purọ́ fún mi. Jọ̀wọ́ sọ bí eniyan ṣe le dè ọ́ lókùn fún mi.” Ó dá a lóhùn pé, “Tí wọ́n bá fi okùn titun, tí wọn kò tíì lò rí dè mí, yóo rẹ̀ mí, n óo sì dàbí àwọn ọkunrin yòókù.” Delila bá mú okùn titun, ó fi dè é, ó sì wí fún un pé, “Samsoni, àwọn ará Filistia dé!” Àwọn tí wọ́n sápamọ́ sì wà ninu yàrá inú. Ṣugbọn Samsoni fa okùn náà já bí ẹni pé fọ́nrán òwú kan ni. Delila tún wí fún Samsoni pé, “Sibẹsibẹ o ṣì tún ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà, o tún ń purọ́ fún mi. Sọ fún mi bí eniyan ṣe lè gbé ọ dè.” Ó dá a lóhùn pé, “Bí o bá di ìdì irun meje tí ó wà lórí mi, mọ́ igi òfì, tí o sì dì í papọ̀, yóo rẹ̀ mi, n óo sì dàbí àwọn ọkunrin yòókù.” Nítorí náà, nígbà tí ó sùn, Delila mú ìdì irun mejeeje tí ó wà lórí rẹ̀, ó lọ́ ọ mọ́ igi òfì, ó sì fi èèkàn kàn án mọ́lẹ̀, ó bá pè é, ó ní, “Samsoni! Àwọn Filistini dé.” Ṣugbọn nígbà tí ó jí láti ojú oorun rẹ̀, ó fa èèkàn ati igi òfì náà tu. Delila tún sọ fún un pé, “Báwo ni o ṣe lè wí pé o nífẹ̀ẹ́ mí, nígbà tí ọkàn rẹ kò sí lọ́dọ̀ mi. O ti fi mí ṣe ẹlẹ́yà nígbà mẹta, o kò sì sọ àṣírí agbára ńlá rẹ fún mi.” Nígbà tí Delila bẹ̀rẹ̀ sí yọ ọ́ lẹ́nu lemọ́lemọ́, tí ó sì ń rọ̀ ọ́ lojoojumọ, ọ̀rọ̀ náà sú Samsoni patapata. Ó bá tú gbogbo ọkàn rẹ̀ palẹ̀ fún Delila, ó ní, “Ẹnìkan kò fi abẹ kàn mí lórí rí, nítorí pé Nasiri Ọlọrun ni mí láti inú ìyá mi wá. Bí wọ́n bá fá irun mi, agbára mi yóo fi mí sílẹ̀, yóo rẹ̀ mí n óo sì dàbí àwọn ọkunrin yòókù.” Nígbà tí Delila rí i pé ó ti tú gbogbo ọkàn rẹ̀ palẹ̀ fún òun, ó ranṣẹ pe àwọn ọba Filistini, ó ní, “Ẹ tún wá lẹ́ẹ̀kan sí i, nítorí pé ó ti sọ gbogbo inú rẹ̀ fún mi.” Àwọn ọba Filistini maraarun bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n mú owó náà lọ́wọ́. Delila mú kí Samsoni sùn lórí ẹsẹ̀ rẹ̀, ó bá pe ọkunrin kan pé kí ó fá ìdì irun mejeeje tí ó wà ní orí Samsoni. Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ẹ́ níyà, agbára rẹ̀ sì fi í sílẹ̀. Ó wí fún un pé, “Samsoni! Àwọn ará Filistia ti dé.” Samsoni bá jí láti ojú oorun, ó ní, “N óo lọ bí mo ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀, n óo sì gba ara mi lọ́wọ́ wọn.” Kò mọ̀ pé OLUWA ti fi òun sílẹ̀. Àwọn Filistini bá kì í mọ́lẹ̀, wọ́n yọ ojú rẹ̀, wọ́n mú un wá sí ìlú Gasa, wọ́n sì fi ẹ̀wọ̀n idẹ dè é. Wọ́n ní kí ó máa lọ àgbàdo ninu ilé ẹ̀wọ̀n. Ṣugbọn irun orí rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí kún lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti fá a. Ní ọjọ́ kan, àwọn ọba Filistini kó ara wọn jọ láti rú ẹbọ ńlá kan sí Dagoni, oriṣa wọn, ati láti ṣe àríyá pé oriṣa wọn ni ó fi Samsoni ọ̀tá wọn lé wọn lọ́wọ́. Nígbà tí àwọn eniyan rí i, wọ́n yin oriṣa wọn; wọ́n ní, “Oriṣa wa ti fi ọ̀tá wa lé wa lọ́wọ́, ẹni tí ó sọ ilẹ̀ wa di ahoro tí ó sì pa ọpọlọpọ ninu wa.” Nígbà tí inú wọn dùn, wọ́n ní, “Ẹ pe Samsoni náà wá, kí ó wá dá wa lára yá.” Wọ́n pe Samsoni jáde láti inú ilé ẹ̀wọ̀n, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí dá wọn lára yá. Wọ́n mú un lọ sí ààrin òpó mejeeji pé kí ó dúró níbẹ̀. Samsoni bá bẹ ọdọmọkunrin tí ó mú un lọ́wọ́, ó ní, “Jẹ́ kí n fi ọwọ́ kan àwọn òpó tí gbogbo ilé yìí gbé ara lé kí n lè fara tì wọ́n.” Ilé náà kún fún ọpọlọpọ eniyan, lọkunrin ati lobinrin; gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Filistini ni wọ́n wà níbẹ̀. Lórí òrùlé nìkan, àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ tó ẹgbẹẹdogun (3,000) eniyan, lọkunrin ati lobinrin tí wọn ń wo Samsoni níbi tí ó ti ń dá wọn lára yá. Samsoni bá ké pe OLUWA, ó ní, “OLUWA Ọlọrun, jọ̀wọ́, ranti mi, kí o sì fún mi lágbára lẹ́ẹ̀kan péré sí i, jọ̀wọ́ Ọlọrun mi, kí n lè gbẹ̀san lára àwọn Filistini fún ọ̀kan ninu ojú mi mejeeji.” Samsoni bá gbá àwọn òpó mejeeji tí ó wà láàrin, tí ilé náà gbára lé mú, ó gbé ọwọ́ ọ̀tún lé ọ̀kan, ó gbé ọwọ́ òsì lé ekeji, ó sì fi gbogbo agbára rẹ̀ tì wọ́n. Ó wí pé, “Jẹ́ kí èmi náà kú pẹlu àwọn ará Filistia.” Ó bá bẹ̀rẹ̀ pẹlu gbogbo agbára rẹ̀. Ilé náà sì wó lu gbogbo àwọn ọba Filistini ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ninu rẹ̀. Nítorí náà, iye eniyan tí ó pa nígbà tí òun náà yóo fi kú, ju àwọn tí ó pa nígbà tí ó wà láàyè lọ. Àwọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ bá wá gbé òkú rẹ̀, wọ́n lọ sin ín sáàrin Sora ati Eṣitaolu ninu ibojì Manoa, baba rẹ̀. Ogún ọdún ni ó fi ṣe aṣiwaju ní Israẹli. Ọkunrin kan wà ní agbègbè olókè ti Efuraimu tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mika. Ó sọ fún ìyá rẹ̀ pé, “Wọ́n gbé ẹẹdẹgbẹfa (1,100) owó fadaka mọ́ ọ lọ́wọ́ nígbà kan, mo sì gbọ́ tí ò ń gbé ẹni tí ó gbé owó náà ṣépè, ọwọ́ mi ni owó náà wà, èmi ni mo gbé e.” Ìyá rẹ̀ dá a lóhùn pé, “OLUWA yóo bukun ọ, ọmọ mi.” Mika gbé ẹẹdẹgbẹfa (1,100) owó fadaka náà pada fún ìyá rẹ̀. Ìyá rẹ̀ bá dáhùn pé, “Mo ya fadaka náà sí mímọ́ fún OLUWA, kí ọmọ mi yá ère fínfín kan kí ó sì yọ́ fadaka náà lé e lórí. Nítorí náà, n óo dá a pada fún ọ.” Nígbà tí Mika kó owó náà fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ mú igba owó fadaka ninu rẹ̀, ó kó o fún alágbẹ̀dẹ fadaka láti yọ́ ọ sórí ère náà, wọ́n sì gbé ère náà sí ilé Mika. Mika ní ojúbọ kan fún ara rẹ̀, ó dá ẹ̀wù funfun kan, ó sì ṣe àwọn ère kéékèèké. Ó fi ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe alufaa oriṣa rẹ̀. Kò sí ọba ní ilẹ̀ Israẹli ní gbogbo àkókò náà, nítorí náà ohun tí ó bá tọ́ lójú olukuluku ni olukuluku ń ṣe. Ọdọmọkunrin kan wà ní Juda, ará Bẹtilẹhẹmu, tí ó jẹ́ ọmọ Lefi láti inú ìdílé Juda, ó ń gbé ibẹ̀. Ọdọmọkunrin náà kó kúrò ní Bẹtilẹhẹmu ní ilẹ̀ Juda, láti lọ máa gbé ibikíbi tí ó bá ti rí ààyè. Bí ó ti ń lọ, ó dé ilé Mika ní agbègbè olókè ti Efuraimu. Mika bá bi í pé, “Níbo ni o ti ń bọ̀?” Ó dá a lóhùn pé, “Ọmọ Lefi, láti Bẹtilẹhẹmu ní ilẹ̀ Juda ni mí, ibi tí n óo máa gbé ni mò ń wá kiri.” Mika bá sọ fún un pè, “Máa gbé ọ̀dọ̀ mi, kí o sì jẹ́ baba ati alufaa fún mi, n óo máa san owó fadaka mẹ́wàá fún ọ lọ́dún. N óo máa dáṣọ fún ọ, n óo sì máa bọ́ ọ.” Ọdọmọkunrin ọmọ Lefi náà gbà, láti máa gbé ọ̀dọ̀ Mika. Mika sì mú un gẹ́gẹ́ bí ọmọ. Mika fi ọdọmọkunrin náà jẹ alufaa, ó sì ń gbé ilé Mika. Mika bá dáhùn pé, “Mo mọ̀ nisinsinyii pé OLUWA yóo bukun mi, nítorí pé, ọmọ Lefi gan-an ni mo gbà gẹ́gẹ́ bí alufaa.” Ní àkókò kan, kò sí ọba ní ilẹ̀ Israẹli, ati pé, ní àkókò náà, àwọn ẹ̀yà Dani ń wá ilẹ̀ tí wọn yóo gbà, tí wọn yóo sì máa gbé, nítorí pé, títí di àkókò yìí wọn kò tíì fún wọn ní ilẹ̀ kankan láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli. Nítorí náà, àwọn ẹ̀yà Dani rán akikanju marun-un láàrin àwọn eniyan wọn, láti ìlú Sora ati Eṣitaolu, kí wọ́n lọ ṣe amí ilẹ̀ náà kí wọ́n sì yẹ̀ ẹ́ wò. Wọ́n wí fún àwọn amí náà pé, “Ẹ lọ kí ẹ sì yẹ ilẹ̀ náà wò.” Wọ́n bá gbéra, wọ́n lọ sí agbègbè olókè ti Efuraimu. Nígbà tí wọ́n dé ilé Mika, wọ́n wọ̀ sibẹ. Nígbà tí wọ́n wà ní ilé Mika, wọ́n ṣàkíyèsí bí ọdọmọkunrin tí ó wà ní ilé Mika ṣe ń sọ̀rọ̀, wọ́n sì mọ̀ pé ọmọ Lefi ni. Wọ́n bá bi í pé, “Ta ló mú ọ wá síhìn-ín? Kí ni ò ń ṣe níhìn-ín? Kí sì ni iṣẹ́ rẹ?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Mika ti bá mi ṣètò, ó ti gbà mí gẹ́gẹ́ bí alufaa rẹ̀.” Wọ́n bá bẹ̀ ẹ́ pé, “Jọ̀wọ́, bá wa wádìí lọ́dọ̀ Ọlọrun, kí á lè mọ̀ bóyá ìrìn àjò tí à ń lọ yìí yóo yọrí sí rere.” Alufaa náà dá wọn lóhùn pé, “Ẹ máa lọ ní alaafia, Ọlọrun fọwọ́ sí ìrìn àjò tí ẹ̀ ń lọ.” Àwọn ọkunrin marun-un náà bá kúrò níbẹ̀, wọ́n wá sí Laiṣi, wọ́n sì rí àwọn eniyan tí wọ́n wà níbẹ̀ bí wọ́n ti ń gbé ní àìléwu gẹ́gẹ́ bí àwọn ará Sidoni tií máa ṣe. Wọ́n ń gbé pọ̀ ní alaafia, kò sí ìjà láàrin wọn, wọ́n ní ohun gbogbo tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n sì ní ọrọ̀. Wọ́n rí i bí wọ́n ti jìnnà sí ibi tí àwọn ará Sidoni wà tó, ati pé wọn kò bá ẹnikẹ́ni da nǹkan pọ̀ ní gbogbo àyíká wọn. Nígbà tí àwọn ọkunrin marun-un náà pada dé ọ̀dọ̀ àwọn eniyan wọn ní Sora ati Eṣitaolu, àwọn eniyan wọn bi wọ́n léèrè pé, “Báwo ni ọ̀hún ti rí?” Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí á lọ gbógun tì wọ́n nítorí pé a ti rí ilẹ̀ náà, ilẹ̀ tí ó lọ́ràá ni. Ẹ má jẹ́ kí á fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀. Ẹ má jáfara, ẹ wọ ilẹ̀ náà, kí ẹ sì gbà á. Nígbà tí ẹ bá lọ, ẹ óo dé ibìkan tí àwọn eniyan ń gbé láìbẹ̀rù, ilẹ̀ náà tẹ́jú. Dájúdájú Ọlọrun ti fi lé yín lọ́wọ́, kò sí ohun tí eniyan ń fẹ́ ní ayé yìí tí kò sí níbẹ̀.” Ẹgbẹta (600) ọkunrin ninu ẹ̀yà Dani tí wọ́n dira ogun gbéra láti Sora ati Eṣitaolu. Wọ́n lọ pàgọ́ sí Kiriati Jearimu ní Juda. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní Mahanedani títí di òní olónìí; ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn Kiriati Jearimu. Wọ́n lọ láti ibẹ̀ sí agbègbè olókè ti Efuraimu, wọ́n dé ilé Mika. Nígbà náà ni àwọn ọkunrin marun-un tí wọ́n lọ ṣe amí ilẹ̀ Laiṣi sọ fún àwọn arakunrin wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé ẹ̀wù efodu kan wà ninu àwọn ilé wọnyi ati àwọn ère kéékèèké, ati ère tí wọ́n gbẹ́ tí wọ́n sì yọ́ fadaka bò lórí, nítorí náà, kí ni ẹ rò pé ó yẹ kí á ṣe?” Wọ́n bá yà sibẹ, wọ́n sì lọ sí ilé ọdọmọkunrin ọmọ Lefi, tí ó wà ní ilé Mika, wọ́n bèèrè alaafia rẹ̀. Àwọn ẹgbẹta (600) ọkunrin ará Dani tí wọ́n dira ogun dúró ní ẹnu ibodè. Àwọn marun-un tí wọ́n lọ ṣe amí ilẹ̀ náà bá wọlé, wọ́n gbé ère dídà, wọn mú ẹ̀wù efodu, wọ́n sì kó àwọn ère kéékèèké ati ère fínfín. Ọdọmọkunrin alufaa yìí sì wà ní ẹnu ibodè pẹlu àwọn ẹgbẹta (600) ọkunrin láti inú ẹ̀yà Dani tí wọ́n ti dira ogun. Nígbà tí àwọn marun-un náà lọ sí ilé Mika tí wọ́n sì kó àwọn ère rẹ̀ ati àwọn nǹkan oriṣa rẹ̀, alufaa náà bi wọ́n léèrè pé, “Irú kí ni ẹ̀ ń ṣe yìí?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Dákẹ́, pa ẹnu rẹ mọ́, kí o sì tẹ̀lé wa, kí o jẹ́ baba ati alufaa fún wa. Èwo ni ìwọ náà rò pé ó dára jù; kí o jẹ́ alufaa fún ilé ẹnìkan ni tabi fún odidi ẹ̀yà kan ati ìdílé kan ní Israẹli?” Inú alufaa náà bá dùn, ó gbé ẹ̀wù efodu, ó kó àwọn ère kékeré náà ati ère dídà náà, ó ń bá àwọn eniyan náà lọ. Wọ́n kúrò níbẹ̀, wọ́n ń lọ. Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́, àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ati àwọn ẹrù wọn ń lọ níwájú wọn. Lẹ́yìn tí wọ́n ti rìn jìnnà sí ilé Mika, Mika pe gbogbo àwọn aládùúgbò rẹ̀ jọ, wọ́n sì lé àwọn ará Dani bá. Wọ́n kígbe pè wọ́n, àwọn ará Dani bá yipada, wọn bi Mika pé, “Kí ní ń dà ọ́ láàmú tí o fi ń bọ̀ pẹlu ọpọlọpọ eniyan báyìí?” Ó bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ kó àwọn oriṣa mi, tí mo dà, ẹ mú alufaa mi lọ; kí ni ó kù mí kù. Ẹ tún wá ń bi mí pé, Kí ló ń ṣe mí?” Àwọn ará Dani dá a lóhùn, wọ́n ní, “Má jẹ́ kí àwọn eniyan gbọ́ ohùn rẹ láàrin wa, kí àwọn tí inú ń bí má baà pa ìwọ ati gbogbo ìdílé rẹ.” Àwọn ará Dani bá ń bá tiwọn lọ, nígbà tí Mika rí i pé wọ́n lágbára ju òun lọ, ó pada sílé rẹ̀. Lẹ́yìn tí àwọn ará Dani ti kó oriṣa Mika, tí wọ́n sì ti gba alufaa rẹ̀, wọ́n lọ sí Laiṣi, wọ́n gbógun ti àwọn eniyan náà níbi tí wọ́n jókòó sí jẹ́jẹ́ láì bẹ̀rù; wọ́n pa wọ́n, wọ́n sì dáná sun ìlú wọn. Kò sì sí ẹnikẹ́ni tí ó lè gbà wọ́n sílẹ̀, nítorí pé wọ́n jìnnà sí ìlú Sidoni, wọn kò sì bá ẹnikẹ́ni ní àyíká wọn da nǹkankan pọ̀. Àfonífojì Betirehobu ni ìlú Laiṣi yìí wà. Wọ́n tún un kọ́, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. Wọ́n yí orúkọ ìlú náà pada kúrò ní Laiṣi tí ó ń jẹ́ tẹ́lẹ̀, wọ́n sọ ọ́ ní Dani gẹ́gẹ́ bí orúkọ baba ńlá wọn tí ó jẹ́ ọmọ bíbí Israẹli. Àwọn ará Dani gbé ère dídà náà kalẹ̀ fún ara wọn. Jonatani ọmọ Geriṣomu, ọmọ Mose ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni wọ́n jẹ́ alufaa fún àwọn ẹ̀yà Dani títí di àkókò tí wọ́n kó gbogbo agbègbè wọn ní ìgbèkùn. Ère tí Mika yá ni wọ́n gbé kalẹ̀, ní gbogbo àkókò tí ilé Ọlọrun fi wà ní Ṣilo. Ní àkókò tí kò sí ọba ní Israẹli, ọmọ Lefi kan ń gbé apá ibìkan tí ó jìnnà ní agbègbè olókè ti Efuraimu. Ọmọ Lefi yìí ní obinrin kan tí ó jẹ́ ará Bẹtilẹhẹmu ni ilẹ̀ Juda. Èdè-àìyedè kan bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn mejeeji, obinrin yìí bá kúrò lọ́dọ̀ ọkunrin náà, ó lọ sí ilé baba rẹ̀ ní Bẹtilẹhẹmu, ó sì ń gbé ibẹ̀ fún nǹkan bí oṣù mẹrin. Lẹ́yìn náà, ọkọ rẹ̀ dìde, ó lọ bẹ̀ ẹ́ pé kí ó pada. Ọkunrin yìí mú iranṣẹ kan ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bíi meji lọ́wọ́. Nígbà tí ó dé ilé baba obinrin rẹ̀ yìí, tí baba iyawo rẹ̀ rí i, ó lọ pàdé rẹ̀ tayọ̀tayọ̀. Baba obinrin náà rọ̀ ọ́ títí ó fi wà pẹlu wọn fún ọjọ́ mẹta; wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì wà níbẹ̀. Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu wọ́n fẹ́ máa lọ. Ṣugbọn baba ọmọbinrin náà rọ̀ ọ́ pé kí ó jẹ oúnjẹ díẹ̀ kí ó tó máa lọ, kí ó lè lágbára. Àwọn ọkunrin mejeeji bá jókòó, wọ́n jẹ, wọ́n mu, lẹ́yìn náà ni baba ọmọbinrin yìí tún dáhùn pé, “Jọ̀wọ́ kúkú dúró ní alẹ́ yìí kí o máa gbádùn ara rẹ.” Nígbà tí ọkunrin náà gbéra, tí ó fẹ́ máa lọ, baba ọmọbinrin náà rọ̀ ọ́ títí tí ó tún fi dúró. Nígbà tí ó di ọjọ́ karun-un, ọkunrin náà gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu láti máa lọ, baba ọmọbinrin náà tún rọ̀ ọ́ pé kí ó fọkàn balẹ̀, kí ó di ìrọ̀lẹ́ kí ó tó máa lọ. Àwọn mejeeji bá jọ jẹun. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́ ọkunrin náà ati obinrin rẹ̀ ati iranṣẹ rẹ̀ gbéra, wọ́n fẹ́ máa lọ; baba ọmọbinrin náà tún wí fún un pé, “Ṣé ìwọ náà rí i pè ilẹ̀ ti ń ṣú lọ, jọ̀wọ́ dúró kí ó di ọ̀la. Ilẹ̀ ló ti ṣú yìí, dúró níhìn-ín kí o sì gbádùn ara rẹ, bí ó bá di ọ̀la kí ẹ bọ́ sọ́nà ní òwúrọ̀ kutukutu, kí ẹ sì máa lọ sílé.” Ṣugbọn ọkunrin náà kọ̀, ó ní òun kò ní di ọjọ́ keji. Ó bá gbéra, ó ń lọ, títí tí wọ́n fi dé ibìkan tí ó dojú kọ Jebusi (tí wọ́n yí orúkọ rẹ̀ pada sí Jerusalẹmu); àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ wà lọ́dọ̀ rẹ̀, obinrin rẹ̀ sì wà pẹlu rẹ̀. Nígbà tí wọ́n súnmọ́ Jebusi, ilẹ̀ ti ń ṣú lọ, iranṣẹ rẹ̀ sọ fún un pé, “Jẹ́ kí á dúró ní ìlú àwọn ará Jebusi yìí kí á sì sùn níbẹ̀ lónìí.” Ó dá a lóhùn, ó ní, “A kò ní wọ̀ ní ìlú àjèjì, lọ́dọ̀ àwọn tí kì í ṣe ọmọ Israẹli, kàkà bẹ́ẹ̀, a óo kọjá lọ sí Gibea.” Ó sọ fún iranṣẹ rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí á lọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú wọnyi, kí á sì sùn ní Gibea tabi ní Rama.” Wọ́n bá tún ń bá ìrìn àjò wọn lọ, oòrùn ti wọ̀ kí wọ́n tó dé Gibea, ọ̀kan ninu àwọn ìlú ẹ̀yà Bẹnjamini. Wọ́n yà sibẹ, láti sùn di ọjọ́ keji. Wọ́n lọ jókòó ní ààrin ìgboro ìlú náà, nítorí pé, ẹnikẹ́ni kò gbà wọ́n sílé pé kí wọ́n sùn di ọjọ́ keji. Nígbà tí ó yá, ọkunrin arúgbó kan ń ti oko bọ̀ ní alẹ́; ará agbègbè olókè Efuraimu ni, ṣugbọn Gibea ni ó ń gbé. Àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini ni wọ́n ń gbé ìlú náà. Bí ó ti gbé ojú sókè, ó rí àwọn àlejò náà ní ìta gbangba láàrin ìgboro ìlú náà; ó sì bi wọ́n léèrè pé, “Níbo ni ẹ̀ ń lọ, níbo ni ẹ sì ti ń bọ̀?” Ọkunrin náà dá a lóhùn pé, “Láti Bẹtilẹhẹmu ti Juda ni a ti ń bọ̀, a sì ń lọ sí ìgbèríko kan ní òpin agbègbè olókè Efuraimu níbi tí mo ti wá. Bẹtilẹhẹmu ti Juda ni mo lọ, mo wá ń pada lọ sílé, nígbà tí a ti dé ìhín, kò sí ẹni tí ó gbà wá sílé. Koríko tí a mú lọ́wọ́ tó fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa, oúnjẹ ati waini tí a sì mú lọ́wọ́ tó fún èmi ati iranṣẹbinrin rẹ ati ọdọmọkunrin tí ó wà pẹlu wa, ìyà ohunkohun kò jẹ wá.” Baba arúgbó náà bá dáhùn pé, “Ṣé alaafia ni ẹ dé? Ẹ kálọ, n óo pèsè ohun gbogbo tí ẹ nílò fun yín, ẹ ṣá má sun ìta gbangba níhìn-ín.” Baba náà bá mú wọn lọ sí ilé rẹ̀, ó fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn ní koríko. Wọ́n ṣan ẹsẹ̀ wọn, wọ́n jẹ, wọ́n sì mu. Bí wọ́n ti ń gbádùn ara wọn lọ́wọ́ ni àwọn ọkunrin lásánlàsàn kan aláìníláárí, ará ìlú náà, bá yí gbogbo ilé náà po, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lu ìlẹ̀kùn. Wọ́n sọ fún baba arúgbó tí ó ni ilé náà pé, “Mú ọkunrin tí ó wọ̀ sinu ilé rẹ jáde, kí á lè bá a lòpọ̀.” Baba arúgbó tí ó ni ilé yìí bá jáde sí wọn, ó bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀ wọ́n, ó ní, “Ẹ̀yin arakunrin mi, ẹ má hu irú ìwà burúkú báyìí, ṣé ẹ rí i pé ọkunrin yìí wá wọ̀ sinu ilé mi ni, ẹ má hu irú ìwà burúkú yìí sí i. Mo ní ọmọbinrin kan tí ó jẹ́ wundia, ọkunrin náà sì ní obinrin kan, ẹ jẹ́ kí n mú wọn jáde sí yín nisinsinyii, kí ẹ sì ṣe wọ́n bí ẹ bá ti fẹ́, kí ẹ tẹ́ ìfẹ́ yín lọ́rùn lára wọn, ṣugbọn ẹ má ṣe hu irú ìwà burúkú yìí sí ọkunrin náà.” Ṣugbọn àwọn ọkunrin náà kọ̀, wọn kò dá a lóhùn. Ó bá ki obinrin ọkunrin náà mọ́lẹ̀, ó tì í sí wọn lóde. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a lòpọ̀ títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, nígbà tí ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mọ́, wọ́n fi sílẹ̀ pé kí ó máa lọ. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, obinrin yìí bá lọ wó lulẹ̀ sì ẹnu ọ̀nà baba arúgbó náà níbi tí ọkunrin tí ó mú un wá wà, ó wà níbẹ̀ títí tí ilẹ̀ fi mọ́ kedere. Ọkunrin yìí bá dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, nígbà tí ó ṣílẹ̀kùn ilé náà tí ó sì jáde pé kí òun máa lọ, òkú obinrin rẹ̀ ni ó rí, tí ó nà sílẹ̀ gbalaja lẹ́nu ọ̀nà, lẹ́bàá ìlẹ̀kùn, pẹlu ọwọ́ tí ó nà tí ó fẹ́ ṣílẹ̀kùn. Ó pè é pé kí ó dìde kí àwọn máa lọ. Ṣugbọn obinrin yìí kò dá a lóhùn. Ó bá gbé òkú rẹ̀ nílẹ̀, ó gbé e sẹ́yìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ó sì lọ sílé rẹ̀. Nígbà tí ó dé ilé, ó mú ọ̀bẹ, ó gé òkú obinrin yìí sí ọ̀nà mejila, ó sì fi wọ́n ranṣẹ sí gbogbo agbègbè Israẹli. Gbogbo àwọn tí wọ́n rí i sì ń wí pé, “A kò rí irú èyí rí láti ọjọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli ti jáde láti ilẹ̀ Ijipti títí di àkókò yìí, ọ̀rọ̀ náà tó àpérò, ẹ gbìmọ̀ ohun tí a ó ṣe, kí ẹ sì sọ̀rọ̀.” Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jáde wá, bẹ̀rẹ̀ láti Dani ní apá ìhà àríwá títí dé Beeriṣeba ní apá ìhà gúsù ilẹ̀ Israẹli ati àwọn tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Gileadi, ní apá ìwọ̀ oòrùn. Wọ́n kó ara wọn jọ sójú kan ṣoṣo níwájú OLUWA ní Misipa. Gbogbo àwọn olórí láàrin àwọn eniyan náà jákèjádò ilẹ̀ Israẹli kó ara wọn jọ pẹlu ìjọ eniyan Ọlọ́run. Àwọn ọmọ ogun tí wọn ń fi ẹsẹ̀ rìn, tí wọ́n sì ń lo idà, tí wọ́n kó ara wọn jọ níbẹ̀ tàwọn ti idà lọ́wọ́ wọn jẹ́ ogún ọ̀kẹ́ (400,000). Àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini gbọ́ pé àwọn ọmọ Israẹli ti kó ara wọn jọ ní Misipa. Àwọn ọmọ Israẹli bèèrè lọ́wọ́ ọmọ Lefi náà pé, “Sọ fún wa, báwo ni nǹkan burúkú yìí ti ṣe ṣẹlẹ̀?” Ọmọ Lefi, ọkọ obinrin tí wọ́n pa, bá dáhùn pé, “Èmi ati obinrin mi ni a yà sí Gibea ní ilẹ̀ àwọn ará Bẹnjamini pé kí á sùn níbẹ̀. Àwọn ọkunrin Gibea bá dìde lóru, wọ́n yí ilé tí mo wà po, wọ́n fẹ́ pa mí. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá obinrin mi lòpọ̀ títí tí ó fi kú. Mo bá gbé òkú rẹ̀, mo gé e lékìrí lékìrí, mo bá fi ranṣẹ sí gbogbo ilẹ̀ Israẹli jákèjádò, nítorí pé àwọn eniyan wọnyi ti ṣe nǹkan burúkú ati ohun ìríra ní Israẹli. Gbogbo ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ gba ọ̀rọ̀ yí yẹ̀wò, kí ẹ sì mú ìmọ̀ràn yín wá lórí rẹ̀ nisinsinyii.” Gbogbo àwọn eniyan náà bá fi ohùn ṣọ̀kan pé, “Ẹnikẹ́ni ninu wa kò ní pada sí àgọ́ rẹ̀ tabi ilé rẹ̀. Ohun tí a óo ṣe nìyí, gègé ni a óo ṣẹ́ láti mọ àwọn tí yóo gbógun ti Gibea. Ìdámẹ́wàá àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ní Israẹli yóo máa pèsè oúnjẹ fún àwọn ọmọ ogun, àwọn yòókù yóo lọ jẹ àwọn ará Gibea níyà fún ìwà burúkú tí wọ́n hù ní Israẹli yìí.” Gbogbo àwọn ọkunrin Israẹli bá kó ara wọn jọ, wọ́n gbógun ti ìlú náà. Àwọn ọmọ Israẹli rán oníṣẹ́ jákèjádò ilẹ̀ Bẹnjamini, wọ́n ní, “Irú ìwà ìkà wo ni ẹ hù yìí? Nítorí náà, ẹ kó àwọn aláìníláárí eniyan tí wọn ń hu ìwà ìkà ní Gibea jáde fún wa, kí á sì pa wọ́n, kí á mú ibi kúrò láàrin Israẹli.” Ṣugbọn àwọn ọmọ Bẹnjamini kò gba ohun tí àwọn arakunrin wọn, àwọn ọmọ Israẹli ń wí. Àwọn ọmọ Bẹnjamini bá kó ara wọn jọ láti gbogbo ìlú ńláńlá, wọ́n wá sí Gibea láti gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ọmọ ogun tí àwọn ará Bẹnjamini kó jọ ní ọjọ́ náà jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaata (26,000) àwọn ọkunrin tí wọn ń lo idà; láì ka àwọn tí wọn ń gbé Gibea tí àwọn náà kó ẹẹdẹgbẹrin (700) akọni ọkunrin jọ. Ẹẹdẹgbẹrin (700) akọni ọkunrin tí wọn ń lo ọwọ́ òsì wà láàrin àwọn ọmọ ogun wọnyi. Wọ́n mọ kànnàkànnà ta, tóbẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé wọ́n lè ta á mọ́ fọ́nrán òwú láì tàsé. Láì ka àwọn tí àwọn ará Bẹnjamini náà kó jọ, àwọn ọmọ Israẹli kó ogún ọ̀kẹ́ (400,000) jagunjagun tí wọn ń lo idà jọ. Àwọn ọmọ Israẹli gbéra lọ sí Bẹtẹli, wọ́n lọ wádìí lọ́dọ̀ Ọlọrun; ẹ̀yà tí yóo kọ́kọ́ gbógun ti ẹ̀yà Bẹnjamini. OLUWA dá wọn lóhùn pé ẹ̀yà Juda ni yóo kọ́kọ́ gbógun tì wọ́n. Àwọn ọmọ Israẹli bá gbéra ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, wọ́n lọ pàgọ́ sí òdìkejì Gibea, wọ́n bá gbógun ti àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini, wọ́n fi ìlú Gibea ṣe ojú ogun wọn. Àwọn ará Bẹnjamini bá jáde sí wọn láti ìlú Gibea, wọ́n sì pa ọ̀kẹ́ kan (20,000) ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli ní ọjọ́ náà. Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli mọ́kàn le, wọ́n tún gbógun tì wọ́n, wọ́n sì tún fi ibi tí wọ́n fi ṣe ojú ogun tẹ́lẹ̀ ṣe ojú ogun wọn. Wọ́n bá lọ sọkún níwájú OLUWA títí di ìrọ̀lẹ́, wọ́n wádìí lọ́dọ̀ OLUWA, wọ́n ní, “Ṣé kí á tún gbógun ti àwọn ará Bẹnjamini tí í ṣe àwọn arakunrin wa?” OLUWA dá wọn lóhùn pé kí wọ́n lọ gbógun tì wọ́n. Àwọn ọmọ Israẹli bá tún lọ gbógun ti àwọn ọmọ ogun Bẹnjamini ní ọjọ́ keji. Àwọn ará Bẹnjamini bá tún jáde láti Gibea ní ọjọ́ keji, wọ́n pa ọ̀kẹ́ kan ó dín ẹgbaa (18,000) eniyan ninu àwọn ọmọ Israẹli, gbogbo wọn jẹ́ jagunjagun tí ń fi idà jà. Gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli bá lọ sí Bẹtẹli, wọ́n jókòó wọ́n sọkún níbẹ̀ níwájú OLUWA, wọ́n gbààwẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́; wọ́n sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia níwájú OLUWA. Àwọn ọmọ Israẹli tún wádìí lọ́dọ̀ OLUWA, nítorí pé àpótí majẹmu Ọlọrun wà ní Bẹtẹli ní àkókò náà. Finehasi ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni ló ń ṣe iṣẹ́ alufaa ní àkókò náà, àwọn ọmọ Israẹli tún bèèrè pé, “Ṣé kí á tún lọ gbógun ti àwọn ará Bẹnjamini tíí ṣe arakunrin wa àbí kí á dáwọ́ dúró?” OLUWA dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ lọ gbógun tì wọ́n, nítorí pé, lọ́la ni n óo fi wọ́n le yín lọ́wọ́.” Àwọn ọmọ Israẹli bá fi àwọn eniyan pamọ́ ní ibùba, yípo gbogbo Gibea. Àwọn ọmọ Israẹli tún gbógun ti àwọn ọmọ Bẹnjamini ní ọjọ́ kẹta, wọ́n tò yípo Gibea bíi ti iṣaaju. Àwọn ará Bẹnjamini jáde sí wọn, àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí fi ọgbọ́n tàn wọ́n kúrò ní ìlú; àwọn ará Bẹnjamini tún bẹ̀rẹ̀ sí pa ninu àwọn ọmọ Israẹli bíi ti iṣaaju. Wọ́n pa wọ́n ní ojú òpópó ọ̀nà tí ó lọ sí Bẹtẹli ati Gibea ati ninu pápá. Àwọn tí wọ́n pa ninu wọ́n tó ọgbọ̀n eniyan. Àwọn ará Bẹnjamini wí fún ara wọn pé, “A tún ti tú wọn ká bíi ti iṣaaju.” Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á sá, kí á sì tàn wọ́n kúrò ninu ìlú wọn, kí wọ́n bọ́ sí ojú òpópó.” Olukuluku àwọn ọmọ Israẹli bá kúrò ní ààyè rẹ̀, wọ́n lọ tò ní Baalitamari. Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ba ní ibùba bá jáde kúrò níbi tí wọ́n ba sí ní apá ìwọ̀ oòrùn Geba. Ni ẹgbaarun (10,000) àṣàyàn àwọn jagunjagun ninu àwọn ọmọ Israẹli bá gbógun ti ìlú Gibea. Ogun náà gbóná gidigidi ṣugbọn àwọn ará Bẹnjamini kò mọ̀ pé ewu ńlá súnmọ́ tòsí wọn. OLUWA bá ṣẹgun àwọn ará Bẹnjamini fún àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ọmọ Israẹli pa ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbẹẹdọgbọn ó lé ọgọrun-un (25,100) eniyan ninu àwọn ará Bẹnjamini lọ́jọ́ náà. Gbogbo àwọn tí wọ́n pa jẹ́ jagunjagun tí wọn ń lo idà. Àwọn ọmọ Bẹnjamini rí i pé wọ́n ti ṣẹgun àwọn. Nígbà tí, àwọn ọmọ Israẹli ṣebí ẹni ń sá lọ fún àwọn ara Bẹnjamini, wọ́n ń tàn wọ́n jáde ni, wọ́n sì ti gbẹ́kẹ̀lé àwọn ará wọn tí wọ́n ba ní ibùba yípo Gibea láti gbógun ti àwọn ará Bẹnjamini. Àwọn tí wọ́n ba ní ibùba yára jáde, wọ́n gbógun ti Gibea, wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn ará ìlú náà run. Àmì tí àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn tí wọ́n ba ní ibùba ti jọ ṣe fún ara wọn ni pé, nígbà tí wọ́n bá rí i tí èéfín ńlá yọ sókè ní Gibea, kí àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ti ń sá lọ yipada, kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jagun. Àwọn ará Bẹnjamini ti pa bí ọgbọ̀n jagunjagun ninu àwọn Israẹli, wọ́n sì ti ń wí ninu ará wọn pé, “Dájúdájú a ti ṣẹgun wọn bíi ti àkọ́kọ́.” Ṣugbọn nígbà tí èéfín tí àwọn ọmọ ogun Israẹli fi ṣe àmì bẹ̀rẹ̀ sí yọ sókè láàrin ìlú, àwọn ará Bẹnjamini wo ẹ̀yìn, wọ́n rí i pé èéfín ti sọ, ó sì ti gba ìlú kan. Àwọn ọmọ Israẹli bá yipada sí wọn, ìdààmú sì bá àwọn ọmọ Bẹnjamini nítorí wọ́n rí i pé ewu ńlá súnmọ́ tòsí. Nítorí náà, wọ́n pada lẹ́yìn àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí ìhà aṣálẹ̀, ṣugbọn ọwọ́ bà wọ́n, nítorí pé ààrin àwọn jagunjagun tí wọ́n yipada sí wọn, ati àwọn tí wọn ń jáde bọ̀ láti inú ìlú ni wọ́n bọ́ sí. Àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n láì dáwọ́ dúró bí wọn ti ń lé wọn lọ. Wọ́n pa wọ́n láti Nohahi títí dé iwájú ìlà oòrùn Gibea. Ọ̀kẹ́ kan ó dín ẹgbaa (18,000) ninu àwọn akikanju ará Bẹnjamini ni àwọn ọmọ Israẹli pa. Wọ́n bá yipada, wọ́n sá gba ọ̀nà aṣálẹ̀ tí ó lọ sí ibi àpáta Rimoni, àwọn ọmọ Israẹli sì tún pa ẹẹdẹgbaata (5,000) ninu wọn ní ojú ọ̀nà. Wọ́n ń lé wọn lọ tete títí dé Gidomu, wọ́n sì tún pa ẹgbaa (2,000) eniyan ninu wọn. Gbogbo àwọn tí wọ́n kú ninu àwọn ọmọ Bẹnjamini ní ọjọ́ náà jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹẹdẹgbaata (25,000); gbogbo wọ́n jẹ́ akikanju jagunjagun tí ń lo idà. Ṣugbọn ẹgbẹta (600) ọkunrin ninu wọn sá lọ sí apá aṣálẹ̀, síbi àpáta Rimoni, wọ́n sì ń gbé inú àpáta Rimoni náà fún oṣù mẹrin. Àwọn ọmọ Israẹli bá yipada sí àwọn ará Bẹnjamini, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pa gbogbo àwọn tí wọ́n bá fojú kàn, ati eniyan ati ẹranko. Gbogbo ìlú wọn tí wọ́n rí ni wọ́n sì sun níná. Àwọn ọmọ Israẹli ti búra nígbà tí wọ́n wà ní Misipa pé, “Ẹnikẹ́ni ninu wa kò ní fi ọmọ rẹ̀ fún ará Bẹnjamini.” Àwọn eniyan bá wá sí Bẹtẹli, wọ́n jókòó níwájú Ọlọrun títí di ìrọ̀lẹ́, wọ́n sì sọkún gidigidi. Wọ́n wí pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, kí ló dé tí irú èyí fi ṣẹlẹ̀ ní Israẹli, tí ó fi jẹ́ pé lónìí ẹ̀yà Israẹli dín kan?” Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, àwọn eniyan náà dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, wọ́n tẹ́ pẹpẹ kan, wọ́n sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia níbẹ̀. Àwọn ọmọ Israẹli bèèrè pé, “Èwo ninu gbogbo ẹ̀yà Israẹli ni kò wá sí ibi àjọ níwájú OLUWA?” Nítorí pé wọ́n ti ṣe ìbúra tí ó lágbára nípa ẹni tí kò bá wá siwaju OLUWA ní Misipa, wọ́n ní, “Pípa ni a óo pa á.” Àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí káàánú àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini arakunrin wọn, wọ́n ní, “Ẹ̀yà Israẹli dín kan lónìí. Báwo ni a óo ṣe rí aya fún àwọn tí ó ṣẹ́kù; nítorí pé a ti fi OLUWA búra pé a kò ní fi àwọn ọmọbinrin wa fún wọn?” Wọ́n bá bèèrè pé, “Ẹ̀yà wo ninu Israẹli ni kò wá siwaju OLUWA ní Misipa?” Wọ́n rí i pé ẹnikẹ́ni kò wá ninu àwọn ará Jabeṣi Gileadi sí àjọ náà. Nítorí pé nígbà tí àwọn eniyan náà kó ara wọn jọ, ẹnikẹ́ni láti inú àwọn tí ń gbé ìlú Jabeṣi Gileadi kò sí níbẹ̀. Ìjọ eniyan náà bá rán ẹgbaafa (12,000) ninu àwọn jagunjagun wọn tí wọ́n gbójú jùlọ, wọ́n sì fún wọn láṣẹ pé, “Ẹ lọ fi idà pa gbogbo àwọn tí ń gbé Jabeṣi Gileadi ati obinrin wọn, ati àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn. Ohun tí ẹ ó ṣe nìyí: gbogbo ọkunrin wọn ati gbogbo obinrin tí ó bá ti mọ ọkunrin, pípa ni kí ẹ pa wọ́n.” Wọ́n rí irinwo (400) ọdọmọbinrin tí kò tíì mọ ọkunrin lára àwọn tí wọn ń gbé ìlú Jabeṣi Gileadi, wọ́n sì kó wọn wá sí àgọ́ ní Ṣilo, tí ó wà ní ilẹ̀ Kenaani. Ni ìjọ eniyan bá ranṣẹ sí àwọn ará Bẹnjamini tí wọ́n wà níbi àpáta Rimoni, pé ìjà ti parí, alaafia sì ti dé. Nígbà náà ni àwọn ará Bẹnjamini tó pada wá, àwọn ọmọ Israẹli sì fún wọn ní àwọn obinrin tí wọ́n mú láàyè ninu àwọn obinrin Jabeṣi Gileadi, ṣugbọn àwọn obinrin náà kò kárí wọn. Àánú àwọn ọmọ Bẹnjamini bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwọn ọmọ Israẹli nítorí pé OLUWA ti dín ọ̀kan kù ninu ẹ̀yà Israẹli. Àwọn àgbààgbà ìjọ eniyan náà bá bèèrè pé, “Níbo ni a óo ti rí aya fún àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù, níwọ̀n ìgbà tí a ti pa àwọn obinrin ẹ̀yà Bẹnjamini run.” Wọ́n bá dáhùn pé, “Àwọn tí wọ́n kù ninu àwọn ara Bẹnjamini gbọdọ̀ ní ogún tiwọn, kí odidi ẹ̀yà kan má baà parun patapata ní Israẹli. Ṣugbọn sibẹsibẹ, a kò gbọdọ̀ fi àwọn ọmọ wa fún wọn.” Nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli ti búra pé, “Ẹni ègún ni ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọmọ fún ará Bẹnjamini.” Wọ́n bá pinnu pé, “Ọdọọdún ni a máa ń ṣe àjọ̀dún OLUWA ní Ṣilo, tí ó wà ní apá àríwá Bẹtẹli, ní apá ìlà oòrùn òpópó ọ̀nà tí ó lọ láti Bẹtẹli sí Ṣekemu, ní apá gúsù Lebona.” Wọ́n bá fún àwọn ọkunrin Bẹnjamini láṣẹ pé, “Ẹ lọ ba ní ibùba ninu ọgbà àjàrà, kí ẹ máa ṣọ́ àwọn ọmọbinrin Ṣilo bí wọ́n bá wá jó; ẹ jáde láti inú ọgbà àjàrà, kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín ki iyawo kọ̀ọ̀kan mọ́lẹ̀ ninu àwọn ọmọbinrin Ṣilo, kí ẹ sì gbé wọn sá lọ sí ilẹ̀ Bẹnjamini. Nígbà tí àwọn baba wọn, tabi àwọn arakunrin wọn bá wá fi ẹjọ́ sùn wá, a óo dá wọn lóhùn pé, ‘Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún wọn nítorí pé àwọn obinrin tí a rí fún wọn ninu ogún kò kárí; kì í kúkú ṣe pé ẹ fi àwọn ọmọbinrin wọnyi fún wọn ni, tí ègún yóo fi ṣẹ le yín lórí.’ ” Àwọn ará Bẹnjamini bá ṣe bí wọ́n ti sọ fún wọn. Olukuluku wọn gbé obinrin kọ̀ọ̀kan sá lọ ninu àwọn tí wọ́n wá jó, gbogbo wọn sì pada lọ sí ilẹ̀ wọn, wọ́n tún ìlú wọn kọ́, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. Àwọn ọmọ Israẹli bá kúrò níbẹ̀, gbogbo wọ́n sì pada sí ilẹ̀ wọn, olukuluku pada lọ sí ìlú rẹ̀, sí ààrin ẹbí rẹ̀. Kò sí ọba ní ilẹ̀ Israẹli ní gbogbo àkókò náà, olukuluku bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bí ó ti tọ́ ní ojú ara rẹ̀. Ní àkókò tí àwọn adájọ́ ń ṣe olórí ní ilẹ̀ Israẹli, ìyàn ńlá kan mú ní ilẹ̀ náà. Ọkunrin kan wà, ará Bẹtilẹhẹmu, ní ilẹ̀ Juda, òun ati aya rẹ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin mejeeji; wọ́n lọ ń gbé ilẹ̀ Moabu. Orúkọ ọkunrin náà ni Elimeleki, aya rẹ̀ ń jẹ́ Naomi, àwọn ọmọkunrin rẹ̀ sì ń jẹ́ Maloni ati Kilioni. Wọ́n kó kúrò ní Efurata ti Bẹtilẹhẹmu, ní ilẹ̀ Juda, wọ́n kó lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Moabu, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. Nígbà tí ó yá, Elimeleki kú, ó bá ku Naomi, opó rẹ̀, ati àwọn ọmọkunrin rẹ̀ mejeeji. Àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji fẹ́ aya láàrin àwọn ọmọ Moabu, Iyawo ẹnikinni ń jẹ́ Opa, ti ẹnìkejì sì ń jẹ́ Rutu. Lẹ́yìn nǹkan bíi ọdún mẹ́wàá tí wọ́n ti jọ ń gbé ilẹ̀ Moabu, Maloni ati Kilioni náà kú, Naomi sì ṣe bẹ́ẹ̀ ṣòfò àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji ati ọkọ rẹ̀. Naomi ati àwọn opó àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji jáde kúrò ní ilẹ̀ Moabu, wọ́n ń pada lọ sí ilẹ̀ Juda, nítorí ó gbọ́ pé OLUWA ti ṣàánú fún àwọn eniyan rẹ̀ ní ilẹ̀ Juda, ati pé wọ́n ti ń rí oúnjẹ jẹ. Òun ati àwọn opó àwọn ọmọ rẹ̀ bá gbéra láti ilẹ̀ Moabu, wọ́n ń lọ sí ilẹ̀ Juda. Bí wọ́n ti ń lọ, Naomi yíjú pada sí àwọn mejeeji, ó ní, “Ẹ̀yin mejeeji, ẹ pada sí ilé ìyá yín. Kí OLUWA ṣàánú fun yín, bí ẹ ti ṣàánú fún èmi ati àwọn òkú ọ̀run. Kí OLUWA ṣe ilé ọkọ tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín bá tún ní, ní ilé rẹ̀.” Ó bá kí wọn, ó fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu, ó dágbére fún wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọkún. Wọ́n dáhùn, wọ́n ní, “Rárá o, a óo bá ọ pada lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan rẹ.” Naomi dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ pada, ẹ̀yin ọmọ mi. Kí ló dé tí ẹ fẹ́ bá mi lọ? Ọmọ wo ló tún kù ní ara mi tí n óo ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, tí yóo ṣú yín lópó? Ẹ pada, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ máa bá tiyín lọ. Ogbó ti dé sí mi, n kò tún lè ní ọkọ mọ́. Bí mo bá tilẹ̀ wí pé mo ní ìrètí, tí mo sì ní ọkọ ní alẹ́ òní, tí mo sì bí àwọn ọmọkunrin, ṣé ẹ óo dúró títí wọn óo fi dàgbà ni, àbí ẹ óo sọ pé ẹ kò ní ní ọkọ mọ́? Kò ṣeéṣe, ẹ̀yin ọmọ mi. Ó dùn mí fun yín pé OLUWA ti bá mi jà.” Wọ́n bá tún bẹ̀rẹ̀ sí sọkún. Nígbà tí ó yá, Opa fi ẹnu ko ìyá ọkọ rẹ̀ lẹ́nu, ó sì dágbére fún un; ṣugbọn Rutu kò kúrò lọ́dọ̀ ìyakọ rẹ̀. Naomi bá sọ fún Rutu, ó ní, “Ṣé o rí i pé arabinrin rẹ ti pada sọ́dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ ati àwọn oriṣa rẹ̀, ìwọ náà pada, kí ẹ jọ máa lọ.” Ṣugbọn Rutu dáhùn, ó ní, “Má pàrọwà fún mi rárá, pé kí n fi ọ́ sílẹ̀, tabi pé kí n pada lẹ́yìn rẹ; nítorí pé ibi tí o bá ń lọ, ni èmi náà yóo lọ; ibi tí o bá ń gbé ni èmi náà yóo máa gbé; àwọn eniyan rẹ ni yóo máa jẹ́ eniyan mi, Ọlọrun rẹ ni yóo sì jẹ́ Ọlọrun mi. Ibi tí o bá kú sí, ni èmi náà yóo kú sí; níbẹ̀ ni wọn yóo sì sin mí sí pẹlu. Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọ yìí, kí OLUWA jẹ́ kí ohun tí ó burú jù bẹ́ẹ̀ lọ bá mi, bí mo bá jẹ́ kí ohunkohun yà mí kúrò lẹ́yìn rẹ, ìbáà tilẹ̀ jẹ́ ikú.” Nígbà tí Naomi rí i pé Rutu ti pinnu ninu ọkàn rẹ̀ láti bá òun lọ, kò sọ ohunkohun mọ́. Àwọn mejeeji bá bẹ̀rẹ̀ sí lọ títí wọ́n fi dé Bẹtilẹhẹmu. Nígbà tí wọ́n wọ Bẹtilẹhẹmu, gbogbo ìlú mì tìtì nítorí wọn. Àwọn obinrin bá bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè pé, “Ṣé Naomi nìyí?” Naomi bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ má pè mí ní Naomi mọ́, Mara ni kí ẹ máa pè mí nítorí pé Olodumare ti jẹ́ kí ayé korò fún mi. Mo jáde lọ ní kíkún, ṣugbọn OLUWA ti mú mi pada ní ọwọ́ òfo, kí ló dé tí ẹ fi ń pè mí ní Naomi, nígbà tí OLUWA fúnra rẹ̀ ti dá mi lẹ́bi, tí Olodumare sì ti mú ìpọ́njú bá mi?” Báyìí ni Naomi ati Rutu, ará Moabu, aya ọmọ rẹ̀, ṣe pada dé láti ilẹ̀ àwọn ará Moabu. Ní àkókò ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà baali ni wọ́n dé sí Bẹtilẹhẹmu. Ní àkókò yìí, ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan wà ninu ìdílé Elimeleki, ẹbí kan náà ni ọkunrin yìí ati ọkọ Naomi. Orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Boasi. Ní ọjọ́ kan, Rutu sọ fún Naomi, ó ní, “Jẹ́ kí n lọ sí oko ẹnìkan, tí OLUWA bá jẹ́ kí n bá ojurere rẹ̀ pàdé, n ó máa ṣa ọkà tí àwọn tí wọ́n ń kórè ọkà bá gbàgbé sílẹ̀.” Naomi bá dá a lóhùn, ó ní, “Ó dára, máa lọ, ọmọ mi.” Rutu bá gbéra, ó lọ sí oko ọkà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣa ọkà tí àwọn tí wọn ń kórè ọkà gbàgbé sílẹ̀. Oko tí ó lọ jẹ́ ti Boasi, ìbátan Elimeleki. Kò pẹ́ pupọ ni Boasi náà dé láti Bẹtilẹhẹmu. Ó kí àwọn tí wọn ń kórè ọkà, ó ní, “Kí OLUWA wà pẹlu yín.” Àwọn náà dáhùn pé, “Kí OLUWA bukun ọ.” Boasi bèèrè lọ́wọ́ ẹni tí ó jẹ́ alákòóso àwọn tí ń kórè, ó ní, “Ọmọ ta ni ọmọbinrin yìí?” Iranṣẹ rẹ̀ náà bá dá a lóhùn, ó ní, “Obinrin ará Moabu, tí ó bá Naomi pada láti ilẹ̀ Moabu ni. Ó bẹ̀ wá pé kí á jọ̀wọ́ kí á fún òun ní ààyè láti máa ṣa ọkà tí àwọn tí wọn ń kórè ọkà bá gbàgbé sílẹ̀. Láti àárọ̀ tí ó ti dé, ni ó ti ń ṣiṣẹ́ títí di àkókò yìí láìsinmi, bí ó ti wù kí ó mọ.” Boasi bá pe Rutu, ó ní, “Gbọ́, ọmọ mi, má lọ sí oko ẹlòmíràn láti ṣa ọkà, má kúrò ní oko yìí, ṣugbọn faramọ́ àwọn ọmọbinrin mi. Oko tí wọn ń kórè rẹ̀ yìí ni kí o kọjú sí, kí o sì máa tẹ̀lé wọn. Mo ti kìlọ̀ fún àwọn ọdọmọkunrin wọnyi pé wọn kò gbọdọ̀ yọ ọ́ lẹ́nu. Nígbà tí òùgnbẹ bá ń gbẹ ọ́, lọ sí ìdí àmù, kí o sì mu ninu omi tí àwọn ọdọmọkunrin wọnyi bá pọn.” Rutu bá wólẹ̀ ó dojúbolẹ̀, ó ní, “Mo dúpẹ́ pé mo rí ojurere lọ́dọ̀ rẹ tó báyìí, o sì ṣe akiyesi mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àlejò ni mí.” Ṣugbọn Boasi dá a lóhùn, ó ní, “Gbogbo ohun tí o ti ṣe fún ìyá ọkọ rẹ, láti ìgbà tí ọkọ rẹ ti kú ni wọ́n ti sọ fún mi patapata, ati bí o ti fi baba ati ìyá rẹ sílẹ̀, tí o kúrò ní ìlú yín, tí o wá sí ọ̀dọ̀ àwọn eniyan tí o kò mọ̀ rí. OLUWA yóo san ẹ̀san gbogbo ohun tí o ti ṣe fún ọ. Abẹ́ ìyẹ́ apá OLUWA Ọlọrun Israẹli ni o wá, fún ààbò, yóo sì fún ọ ní èrè kíkún.” Rutu bá dáhùn, ó ní, “O ṣàánú mi gan-an ni, oluwa mi, nítorí pé o ti tù mí ninu, o sì ti fi sùúrù bá èmi iranṣẹbinrin rẹ sọ̀rọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kì í ṣe ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹbinrin rẹ.” Nígbà tí àkókò oúnjẹ tó, Boasi pe Rutu, ó ní, “Wá jẹun, kí o fi òkèlè rẹ bọ inú ọtí kíkan.” Rutu bá jókòó lọ́dọ̀ àwọn tí wọn ń kórè ọkà, Boasi gbé ọkà yíyan nawọ́ sí i; ó sì jẹ àjẹyó ati àjẹṣẹ́kù. Nígbà tí Rutu dìde, láti tún máa ṣa ọkà, Boasi pàṣẹ fún àwọn ọdọmọkunrin rẹ̀, ó ní, “Ẹ jẹ́ kí ó máa ṣa ọkà láàrin àwọn ìtí ọkà tí ẹ dì jọ, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ yọ ọ́ lẹ́nu. Kí ẹ tilẹ̀ fa ọkà yọ fún un ninu ìtí, kí ẹ sì tún fi í sílẹ̀ láti ṣa ọkà, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ yọ ọ́ lẹ́nu.” Rutu bá tún bẹ̀rẹ̀ sí ṣa ọkà. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, ó pa ọkà tí ó ṣà, ohun tí ó rí tó ìwọ̀n efa ọkà baali kan. Ó gbé e, ó sì lọ sílé. Ó fi ọkà tí ó rí han ìyá ọkọ rẹ̀, ó sì fún un ní oúnjẹ tí ó jẹ kù. Ìyá ọkọ rẹ̀ bi í léèrè, ó ní, “Níbo ni o ti ṣa ọkà lónìí, níbo ni o sì ti ṣiṣẹ́? OLUWA yóo bukun ẹni tí ó ṣàkíyèsí rẹ.” Rutu bá sọ inú oko ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́ fún ìyá ọkọ rẹ̀, ó ní, “Inú oko ọkunrin kan tí wọ́n ń pè ní Boasi ni mo ti ṣa ọkà lónìí.” Naomi dáhùn, ó ní, “Kí OLUWA tí kì í gbàgbé láti ṣàánú ati òkú ọ̀run, ati alààyè bukun Boasi.” Naomi bá ṣe àlàyé fún Rutu pé, ẹbí àwọn ni Boasi, ati pé ọ̀kan ninu àwọn tí ó súnmọ́ wọn pẹ́kípẹ́kí ni. Rutu tún fi kún un fún Naomi pé, “Boasi tilẹ̀ tún wí fún mi pé, n kò gbọdọ̀ jìnnà sí àwọn iranṣẹ òun títí tí wọn yóo fi parí ìkórè ọkà Baali rẹ̀.” Naomi dáhùn, ó ní, “Ó dára, máa bá àwọn ọmọbinrin rẹ̀ lọ, ọmọ mi, kí wọ́n má baà yọ ọ́ lẹ́nu bí o bá lọ sinu oko ọkà ẹlòmíràn.” Rutu bá ń bá àwọn ọmọbinrin Boasi lọ láti ṣa ọkà títí wọ́n fi parí ìkórè ọkà Baali, ó sì ń gbé ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, Naomi pe Rutu, ó ní, “Ọmọ mi, ó tó àkókò láti wá ọkọ fún ọ, kí ó lè dára fún ọ. Ṣé o ranti pé ìbátan wa ni Boasi, tí o wà pẹlu àwọn ọmọbinrin rẹ̀? Wò ó, yóo lọ fẹ́ ọkà baali ní ibi ìpakà rẹ̀ lálẹ́ òní. Nítorí náà, lọ wẹ̀, kí o sì fi nǹkan pa ara. Wọ aṣọ rẹ tí ó dára jùlọ, kí o sì lọ sí ibi ìpakà rẹ̀, ṣugbọn má jẹ́ kí ó mọ̀ pé o wà níbẹ̀ títí di ìgbà tí ó bá jẹ tí ó sì mu tán. Nígbà tí ó bá fẹ́ sùn, ṣe akiyesi ibi tí ó sùn sí dáradára, lẹ́yìn náà, lọ ṣí aṣọ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀, kí o sì sùn tì í, lẹ́yìn náà, yóo sọ ohun tí o óo ṣe fún ọ.” Rutu bá dá Naomi lóhùn, ó ní, “Gbogbo ohun tí o sọ fún mi ni n óo ṣe.” Rutu bá lọ sí ibi ìpakà, ó ṣe bí ìyá ọkọ rẹ̀ ti sọ fún un. Nígbà tí Boasi jẹ, tí ó mu tán, tí inú rẹ̀ sì dùn, ó lọ sùn lẹ́yìn òkítì ọkà Baali tí wọ́n ti pa. Rutu bá rọra lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó ṣí aṣọ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì sùn tì í. Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́ òru, Boasi tají lójijì, bí ó ti yí ara pada, ó rí i pé obinrin kan sùn ní ibi ẹsẹ̀ òun. Ó bá bèèrè, pé, “Ìwọ ta ni?” Rutu dáhùn, ó ní, “Èmi Rutu, iranṣẹbinrin rẹ ni. Da aṣọ rẹ bo èmi iranṣẹbinrin rẹ, nítorí pé ìwọ ni ìbátan tí ó súnmọ́ ọkọ mi jùlọ.” Boasi bá dáhùn, ó ní, “OLUWA yóo bukun fún ọ, ọmọ mi, oore tí o ṣe ní ìkẹyìn yìí tóbi ju ti àkọ́kọ́ lọ; nítorí pé o kò wá àwọn ọdọmọkunrin lọ, kì báà jẹ́ olówó tabi talaka. Má bẹ̀rù, ọmọ mi, gbogbo ohun tí o bèèrè ni n óo ṣe fún ọ, nítorí pé gbogbo àwọn ọkunrin ẹlẹgbẹ́ mi ní ilẹ̀ yìí ni wọ́n mọ̀ pé obinrin gidi ni ọ́. Òtítọ́ ni mo jẹ́ ìbátan tí ó súnmọ́ ọkọ rẹ, ṣugbọn ẹnìkan wà tí ó tún súnmọ́ ọn jù mí lọ. Sùn títí di òwúrọ̀, nígbà tí ó bá di òwúrọ̀ bí ó bá tẹ́ ẹ lọ́rùn láti ṣú ọ lópó gẹ́gẹ́ bí ẹ̀tọ́ rẹ̀, ó dára, jẹ́ kí ó ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣugbọn bí kò bá fẹ́ ṣe ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìbátan, bí OLUWA ti wà láàyè, n óo ṣe ẹ̀tọ́, gẹ́gẹ́ bí ìbátan tí ó súnmọ́ ọn. Sùn títí di òwúrọ̀.” Rutu bá sùn lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀ títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, ṣugbọn ó tètè dìde ní àfẹ̀mọ́jú, kí eniyan tó lè dá eniyan mọ̀. Boasi bá kìlọ̀ fún un pé, “Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ mọ̀ pé o wá sí ibi ìpakà.” Boasi sọ fún un pe kí ó tẹ́ aṣọ ìlékè rẹ̀, kí ó sì fi ọwọ́ mú un, Rutu náà sì ṣe bẹ́ẹ̀. Boasi wọn ìwọ̀n ọkà Baali mẹfa sinu aṣọ náà, ó dì í, ó gbé e ru Rutu, Rutu sì pada sí ilé. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ rẹ̀, ìyá ọkọ rẹ̀ bi í pé, “Báwo ni ibẹ̀ ti rí, ọmọ mi?” Rutu bá sọ gbogbo ohun tí ọkunrin náà ṣe fún un. Ó ní, “Ìwọ̀n ọkà Baali mẹfa ni ó dì fún mi, nítorí ó sọ pé n kò gbọdọ̀ pada sí ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ mi ní ọwọ́ òfo.” Naomi bá dáhùn, ó ní, “Fara balẹ̀ ọmọ mi, títí tí o óo fi gbọ́ bí ọ̀rọ̀ náà yóo ti yọrí sí; nítorí pé ara ọkunrin yìí kò ní balẹ̀ títí tí yóo fi yanjú ọ̀rọ̀ náà lónìí.” Boasi bá lọ sí ẹnu ibodè ìlú, ó jókòó níbẹ̀. Bí ìbátan ọkọ Rutu tí ó súnmọ́ ọn, tí Boasi sọ nípa rẹ̀ ti ń kọjá lọ, ó pè é, ó ní, “Ọ̀rẹ́, yà sí ibí, kí o sì jókòó.” Ọkunrin náà bá yà, ó sì jókòó. Boasi pe àwọn mẹ́wàá ninu àwọn àgbààgbà ìlú, ó ní, “Ẹ wá jókòó sí ibí.” Wọ́n bá jókòó. Lẹ́yìn náà, ó pe ìbátan ọkọ Rutu yìí, ó ní, “Naomi tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ilẹ̀ àwọn ará Moabu pada dé, fẹ́ ta ilẹ̀ kan tí ó jẹ́ ti Elimeleki ìbátan wa. Nítorí náà, mo rò ó ninu ara mi pé, kí n kọ́ sọ fún ọ pé kí o rà á, níwájú àwọn tí wọ́n jókòó níhìn-ín, ati níwájú àwọn àgbààgbà, àwọn eniyan wa; bí o bá gbà láti rà á pada, rà á. Ṣugbọn bí o kò bá fẹ́ rà á pada, sọ fún mi, kí n lè mọ̀, nítorí pé kò sí ẹni tí ó tún lè rà á pada, àfi ìwọ, èmi ni mo sì tẹ̀lé ọ.” Ọkunrin yìí dáhùn pé òun óo ra ilẹ̀ náà pada. Boasi bá fi kún un pé, “Ọjọ́ tí o bá ra ilẹ̀ yìí ní ọwọ́ Naomi, bí o bá ti ń ra ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni óo ra Rutu, ará ilẹ̀ Moabu, opó ọmọ Naomi; kí orúkọ òkú má baà parun lára ogún rẹ̀.” Ìbátan Elimeleki yìí dáhùn, ó ní, “Bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, n kò ní lè ra ilẹ̀ náà pada, nítorí kò ní jẹ́ kí àwọn ọmọ tèmi lè jogún mi bí ó ti yẹ. Bí o bá fẹ́, o lè fi ọwọ́ mú ohun tí ó jẹ́ ẹ̀tọ́ mi yìí, nítorí pé n kò lè rà á pada.” Ní àkókò yìí, ohun tí ó jẹ́ àṣà àwọn ọmọ Israẹli nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ètò ìràpada ati pàṣípààrọ̀ ohun ìní ni pé ẹni tí yóo bá ta nǹkan yóo bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀, yóo sì kó o fún ẹni tí yóo rà á. Bàtà yìí ni ó dàbí ẹ̀rí ati èdìdì láàrin ẹni tí ń ta nǹkan ati ẹni tí ń rà á, ní ilẹ̀ Israẹli. Nítorí náà, nígbà tí ìbátan náà wí fún Boasi pé, “Rà á bí o bá fẹ́.” Ó bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀ fún Boasi, Boasi bá sì sọ fún àwọn àgbààgbà ati gbogbo àwọn eniyan, ó ní, “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí lónìí pé mo ti ra gbogbo ohun tí ó jẹ́ ti Elimeleki ati ti Kilioni ati ti Maloni lọ́wọ́ Naomi. Ati pé, mo ṣú Rutu, ará Moabu, opó Maloni lópó, ó sì di aya mi; kí orúkọ òkú má baà parun lára ohun ìní rẹ̀, ati pé kí á má baà mú orúkọ rẹ̀ kúrò láàrin àwọn arakunrin rẹ̀ ati ní ẹnu ọ̀nà àtiwọ ìlú baba rẹ̀. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí lónìí.” Gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ní ẹnu ọ̀nà ibodè ati àwọn àgbààgbà náà dáhùn pé, “Àwa ni ẹlẹ́rìí, kí OLUWA kí ó ṣe obinrin tí ń bọ̀ wá di aya rẹ bíi Rakẹli ati Lea, tí wọ́n bí ọpọlọpọ ọmọ fún Jakọbu. Yóo dára fún ọ ní Efurata, o óo sì di olókìkí ní Bẹtilẹhẹmu. Àwọn ọmọ tí OLUWA yóo jẹ́ kí obinrin yìí bí fún ọ yóo kún ilé rẹ fọ́fọ́, bí ọmọ ti kún ilé Peresi, tí Tamari bí fún Juda.” Boasi bá ṣú Rutu lópó, Rutu sì di aya rẹ̀. Nígbà tí Boasi bá a lòpọ̀, ó lóyún, ó bí ọmọkunrin kan. Àwọn obinrin bá sọ fún Naomi pé, “Ìyìn ni fún OLUWA, tí kò ṣe ọ́ ní aláìní ìbátan, kí OLUWA ṣe ọmọ náà ní olókìkí ní Israẹli. Ọmọ yìí yóo mú kí adùn ayé rẹ sọjí, yóo sì jẹ́ olùtọ́jú fún ọ ní ọjọ́ ogbó rẹ, nítorí iyawo ọmọ rẹ tí ó fẹ́ràn rẹ, tí ó sì ju ọmọkunrin meje lọ ni ó bímọ fún ọ.” Naomi bá gba ọmọ náà, ó tẹ́ ẹ sí àyà rẹ̀, ó sì di olùtọ́jú rẹ̀. Àwọn obinrin àdúgbò bá sọ ọmọ náà ní Obedi, wọ́n ń sọ káàkiri pé, “A bí ọmọkunrin kan fún Naomi.” Obedi yìí ni baba Jese tíí ṣe baba Dafidi. Àwọn atọmọdọmọ Peresi nìwọ̀nyí: Peresi ni baba Hesironi; Hesironi bí Ramu, Ramu bí Aminadabu; Aminadabu bí Naṣoni; Naṣoni bí Salimoni; Salimoni bí Boasi, Boasi bí Obedi; Obedi bí Jese, Jese sì bí Dafidi. Ọkunrin kan wà ninu ẹ̀yà Efuraimu tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Elikana, ará Ramataimu-sofimu, ní agbègbè olókè Efuraimu. Orúkọ baba rẹ̀ ni Jerohamu, ọmọ Elihu, ọmọ Tohu, láti ìdílé Sufu, ará Efuraimu. Iyawo meji ni Elikana yìí ní. Ọ̀kan ń jẹ́ Hana, ekeji sì ń jẹ́ Penina. Penina bímọ, ṣugbọn Hana kò bí. Ní ọdọọdún ni Elikana máa ń ti Ramataimu-sofimu lọ sí Ṣilo láti lọ sin OLUWA àwọn ọmọ ogun, ati láti rúbọ sí i. Hofini ati Finehasi, àwọn ọmọ Eli, ni alufaa OLUWA níbẹ̀. Ní ọjọ́ tí Elikana bá rú ẹbọ rẹ̀, a máa fún Penina ní ìdá kan ninu nǹkan tí ó bá fi rúbọ, a sì máa fún àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin ní ìdá kọ̀ọ̀kan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fẹ́ràn Hana, sibẹ ìdá kan ní í máa ń fún un, nítorí pé OLUWA kò fún un ní ọmọ bí. Penina, orogún Hana, a máa fín in níràn gidigidi, kí ó baà lè mú un bínú, nítorí pé OLUWA kò fún un ní ọmọ bí. Ní ọdọọdún tí wọ́n bá ti lọ sí ilé OLUWA ni Penina máa ń mú Hana bínú tóbẹ́ẹ̀ tí Hana fi máa ń sọkún, tí kò sì ní jẹun. Ọkọ rẹ̀ a máa rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún, a máa bi í pé, “Kí ní ń pa ọ́ lẹ́kún? Kí ló dé tí o kò jẹun? Kí ní ń bà ọ́ lọ́kàn jẹ́? Ṣé n kò wá ju ọmọ mẹ́wàá lọ fún ọ ni?” Ní ọjọ́ kan, lẹ́yìn tí wọ́n jẹ, tí wọ́n mu tán, ninu ilé OLUWA, ní Ṣilo, Hana dìde. Eli, alufaa wà ní ìjókòó lórí àpótí, lẹ́bàá òpó ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA. Inú Hana bàjẹ́ gan-an, ó bẹ̀rẹ̀ sí gbadura sí OLUWA, ó sì ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn. Hana bá OLUWA jẹ́jẹ̀ẹ́ ó ní, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, bí o bá ṣíjú wo ìyà tí èmi iranṣẹ rẹ ń jẹ, tí o kò gbàgbé mi, tí o fún mi ní ọmọkunrin kan, n óo ya ọmọ náà sọ́tọ̀ fún ìwọ OLUWA ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, abẹ kò sì ní kàn án lórí.” Bí Hana ti ń gbadura sí OLUWA, Eli ń wo ẹnu rẹ̀. Hana ń gbadura ninu ọkàn rẹ̀, kìkì ètè rẹ̀ nìkan ní ń mì, ẹnikẹ́ni kò gbọ́ ohun tí ó ń sọ. Nítorí náà, Eli rò pé ó ti mu ọtí yó ni. Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí bá a wí pé, “O óo ti mu ọtí waini pẹ́ tó? Sinmi ọtí mímu.” Hana dá a lóhùn, pé, “Rárá o, oluwa mi, n kò fẹnu kan ọtí waini tabi ọtí líle. Ìbànújẹ́ ló bá mi, tóbẹ́ẹ̀ tí mo fi ń gbadura, tí mo sì ń tú ọkàn mi jáde fún OLUWA. Má rò pé ọ̀kan ninu àwọn oníranù obinrin ni mí. Ninu ìbànújẹ́ ńlá ati àníyàn ni mò ń gbadura yìí.” Eli bá dá a lóhùn, ó ní, “Máa lọ ní alaafia, Ọlọrun Israẹli yóo fún ọ ní ohun tí ò ń tọrọ lọ́wọ́ rẹ̀.” Hana bá dá a lóhùn pé, “Jẹ́ kí èmi, iranṣẹbinrin rẹ, bá ojurere rẹ pàdé.” Ó bá dìde, ó jẹun, ó dárayá, kò sì banújẹ́ mọ́. Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, Elikana ati ìdílé rẹ̀ múra, wọ́n sì sin OLUWA. Lẹ́yìn náà, wọ́n gbéra, wọ́n pada sí ilé wọn, ní Rama. Nígbà tí ó yá, Elikana bá Hana lòpọ̀, OLUWA sì gbọ́ adura rẹ̀. Hana lóyún, ó bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọmọ náà ní Samuẹli, ó ní, “Títọrọ ni mo tọrọ rẹ̀ lọ́wọ́ OLUWA.” Nígbà tí ó yá, àkókò tó fún Elikana ati ìdílé rẹ̀ láti lọ sí Ṣilo, láti lọ rú ẹbọ ọdọọdún, kí Elikana sì san ẹ̀jẹ́ tí ó jẹ́ fún OLUWA. Ṣugbọn Hana kò bá wọn lọ. Ó wí fún ọkọ rẹ̀ pé, “Bí mo bá ti gba ọmú lẹ́nu ọmọ yìí ni n óo mú un lọ sí ilé OLUWA, níbẹ̀ ni yóo sì máa gbé títí ọjọ́ ayé rẹ̀.” Elikana dá a lóhùn pé, “Ṣe bí ó bá ti tọ́ ní ojú rẹ. Dúró ní ilé, títí tí o óo fi gba ọmú lẹ́nu rẹ̀. Kí OLUWA jẹ́ kí o lè mú ìlérí rẹ ṣẹ.” Hana bá dúró ní ilé, ó ń tọ́jú ọmọ náà. Nígbà tí ó gba ọmú lẹ́nu rẹ̀, ó mú un lọ́wọ́ lọ sí Ṣilo. Nígbà tí ó ń lọ, ó mú akọ mààlúù ọlọ́dún mẹta kan lọ́wọ́, ati ìyẹ̀fun ìwọ̀n efa kan, ati ọtí waini ẹ̀kún ìgò aláwọ kan. Ó sì mú Samuẹli lọ sí Ṣilo ní ilé OLUWA, ọmọde ni Samuẹli nígbà náà. Lẹ́yìn tí wọ́n ti pa akọ mààlúù náà tán, wọ́n mú Samuẹli tọ Eli lọ. Hana bèèrè lọ́wọ́ Eli pé, “Oluwa mi, ǹjẹ́ o ranti mi mọ́? Èmi ni obinrin tí o rí níjelòó, tí mo dúró níhìn-ín níwájú rẹ, tí mò ń gbadura sí OLUWA. Ọmọ yìí ni mò ń tọrọ lọ́wọ́ OLUWA, ó sì fún mi ní ohun tí mo bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Nítorí náà, mo wá ya ọmọ náà sọ́tọ̀ fún OLUWA, ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ yóo jẹ́ ti OLUWA.” Lẹ́yìn náà, wọ́n sin OLUWA níbẹ̀. Hana bá gbadura báyìí pé: “Ọkàn mi kún fún ayọ̀ ninu OLUWA, Ó sọ mí di alágbára; mò ń fi àwọn ọ̀tá mi rẹ́rìn-ín, nítorí mò ń yọ̀ pé OLUWA gbà mí là. “Kò sí ẹni mímọ́ bíi OLUWA, kò sí ẹlòmíràn, àfi òun nìkan ṣoṣo. Kò sí aláàbò kan tí ó dàbí Ọlọrun wa. Má sọ̀rọ̀ pẹlu ìgbéraga mọ́, má jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìgbéraga ti ẹnu rẹ jáde, nítorí Ọlọrun tí ó mọ ohun gbogbo ni OLUWA, gbogbo ohun tí ẹ̀dá bá ṣe ni ó sì máa ń gbéyẹ̀wò. Ọrun àwọn alágbára dá, ṣugbọn àwọn aláìlágbára di alágbára. Àwọn tí wọ́n rí oúnjẹ jẹ lájẹyó rí ti di ẹni tí ń fi ara wọn ṣọfà nítorí oúnjẹ, ṣugbọn àwọn tí ebi ti ń pa tẹ́lẹ̀ rí tí ń jẹ àjẹyó. Àgàn ti di ọlọ́mọ meje, ọlọ́mọ pupọ ti di aláìní. OLUWA ni ó lè pa eniyan tán, kí ó sì tún jí i dìde; òun ni ó lè múni lọ sinu isà òkú, tí ó sì tún lè fani yọ kúrò níbẹ̀. OLUWA ni ó lè sọni di aláìní, òun náà ni ó sì lè sọ eniyan di ọlọ́rọ̀. Òun ni ó ń gbéni ga, òun náà ni ó sì ń rẹ eniyan sílẹ̀. OLUWA ń gbé talaka dìde láti ipò ìrẹ̀lẹ̀; ó ń gbé aláìní dìde láti inú òṣì rẹ̀, láti mú wọn jókòó pẹlu àwọn ọmọ ọba, kí wọ́n sì wà ní ipò ọlá. Nítorí pé òun ni ó ni àwọn ìpìlẹ̀ ayé, òun ni ó sì gbé ayé kalẹ̀ lórí wọn. “Yóo pa àwọn olóòótọ́ tí wọ́n jẹ́ tirẹ̀ mọ́, ṣugbọn yóo mú kí àwọn eniyan burúkú parẹ́ ninu òkùnkùn; nítorí pé, kì í ṣe nípa agbára eniyan, ni ẹnikẹ́ni lè fi ṣẹgun. Àwọn ọ̀tá OLUWA yóo parun; OLUWA yóo sán ààrá pa wọ́n láti ojú ọ̀run wá. OLUWA yóo ṣe ìdájọ́ gbogbo ayé, yóo fún ọba rẹ̀ lágbára, yóo sì fún ẹni tí ó yàn ní ìṣẹ́gun.” Lẹ́yìn náà, Elikana pada sí ilé rẹ̀ ní Rama. Ṣugbọn Samuẹli dúró sí Ṣilo, ó ń ṣiṣẹ́ iranṣẹ sin OLUWA, lábẹ́ alufaa Eli. Aláìníláárí ẹ̀dá ni àwọn ọmọ Eli mejeeji. Wọn kò bọ̀wọ̀ fún OLUWA rárá. Ó jẹ́ àṣà àwọn alufaa pé nígbà tí ẹnìkan bá wá rúbọ, iranṣẹ alufaa yóo wá, ti òun ti ọ̀pá irin oníga mẹta tí wọ́n fi ń yọ ẹran lọ́wọ́ rẹ̀. Nígbà tí wọ́n bá ń se ẹran náà lọ́wọ́ lórí iná, yóo ti ọ̀pá irin náà bọ inú ìkòkò ẹran, gbogbo ẹran tí ó bá yọ jáde á jẹ́ ti alufaa. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n máa ń ṣe sí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n bá wá rúbọ ní Ṣilo. Ati pé, kí wọ́n tilẹ̀ tó rẹ́ ọ̀rá tí wọ́n máa ń sun kúrò lára ẹran, iranṣẹ alufaa á wá, a sì wí fún ẹni tí ń rú ẹbọ pé kí ó fún òun ninu ẹran tí alufaa yóo sun jẹ, nítorí pé alufaa kò ní gba ẹran bíbọ̀ lọ́wọ́ olúwarẹ̀, àfi ẹran tútù. Bí ẹni tí ń rú ẹbọ náà bá dá a lóhùn pé “Jẹ́ kí á kọ́kọ́ sun ọ̀rá ẹran náà, lẹ́yìn náà kí o wá mú ohun tí ó bá wù ọ́.” Iranṣẹ alufaa náà á wí pé, “Rárá! Nisinsinyii ni kí o fún mi, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, n óo mú un tipátipá.” Ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn ọmọ Eli ń dá yìí burú pupọ lójú OLUWA, nítorí pé wọn kò náání ẹbọ OLUWA. Ní gbogbo àkókò yìí, Samuẹli ń ṣe iṣẹ́ iranṣẹ sin OLUWA, ó sì jẹ́ ọmọde nígbà náà, a máa wọ ẹ̀wù efodu funfun. Ní ọdọọdún ni ìyá rẹ̀ máa ń dá ẹ̀wù kékeré, a sì mú un lọ́wọ́ lọ fún un, nígbà tí ó bá bá ọkọ rẹ̀ lọ, láti lọ rúbọ. Eli a máa súre fún Elikana ati Hana aya rẹ̀ pé, “OLUWA yóo jẹ́ kí obinrin yìí bí ọmọ mìíràn fún ọ, dípò èyí tí ó yà sọ́tọ̀ fún OLUWA.” Lẹ́yìn náà, wọn yóo pada lọ sí ilé wọn. OLUWA bukun Hana: ọmọkunrin mẹta, ati ọmọbinrin meji ni ó tún bí lẹ́yìn Samuẹli. Samuẹli sì ń dàgbà níbi tí ó ti ń ṣe iṣẹ́ iranṣẹ sin OLUWA. Eli ti di arúgbó gan-an ní àkókò yìí. Ó ń gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn ọmọ rẹ̀ ń ṣe sí àwọn ọmọ Israẹli, ati bí wọ́n ti ṣe ń bá àwọn obinrin tí wọn ń ṣiṣẹ́ ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ lòpọ̀. A máa bi wọ́n léèrè pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe báyìí? Gbogbo ìwà burúkú tí ẹ̀ ń hù sí àwọn eniyan ni mò ń gbọ́. Ẹ̀yin ọmọ mi, ọ̀rọ̀ burúkú ni àwọn eniyan OLUWA ń sọ káàkiri nípa yín. Bí ẹnìkan bá ṣẹ eniyan, Ọlọrun lè parí ìjà láàrin wọn; ṣugbọn bí eniyan bá ṣẹ OLUWA, ta ni yóo bá a bẹ̀bẹ̀?” Ṣugbọn àwọn ọmọ Eli kò gbọ́ ti baba wọn, nítorí pé OLUWA ti pinnu láti pa wọ́n. Samuẹli ń dàgbà sí i, ó sì ń bá ojurere OLUWA ati ti eniyan pàdé. OLUWA rán wolii kan sí Eli, kí ó sọ fún un pé, “Mo fara han ìdílé baba rẹ nígbà tí wọ́n jẹ́ ẹrú Farao ọba ní ilẹ̀ Ijipti. Ninu gbogbo ẹ̀yà tí ó wà ní Israẹli, ìdílé baba rẹ nìkan ni mo yàn láti jẹ́ alufaa mi, pé kí ẹ máa ṣe iṣẹ́ alufaa níbi pẹpẹ, kí ẹ máa sun turari kí ẹ máa wọ ẹ̀wù efodu, kí ẹ sì máa wádìí nǹkan lọ́wọ́ mi. Mo fún wọn ní gbogbo ẹbọ sísun tí àwọn ọmọ Israẹli bá rú sí mi. Kí ló dé tí o fi ń ṣe ojúkòkòrò sí ọrẹ ati ẹbọ tí mo bèèrè lọ́wọ́ àwọn eniyan mi, tí o sì gbé àwọn ọmọ rẹ ga jù mí lọ; tí wọn ń jẹ àwọn ohun tí ó dára jùlọ lára ohun tí àwọn eniyan mi bá fi rúbọ sí mi ní àjẹyọkùn? Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun Israẹli ni mo sọ pé, mo ti ṣèlérí tẹ́lẹ̀ pé, ìdílé rẹ ati ìdílé baba rẹ ni yóo máa jẹ́ alufaa mi títí lae. Ṣugbọn nisinsinyii, èmi OLUWA náà ni mo sì tún ń sọ pé, kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́, nítorí pé àwọn tí wọ́n bá bu ọlá fún mi ni n óo máa bu ọlá fún, àwọn tí wọn kò bá kà mí sí, n kò ní ka àwọn náà sí. Wò ó! Àkókò ń bọ̀ tí n óo run gbogbo àwọn ọdọmọkunrin ìdílé rẹ ati ti baba rẹ kúrò, débi pé kò ní sí àgbà ọkunrin kan ninu ìdílé rẹ mọ́. Pẹlu ìbànújẹ́ ni o óo máa fi ìlara wo bí OLUWA yóo ṣe bukun Israẹli, kò sì ní sí àgbàlagbà ọkunrin ninu ìdílé rẹ mọ́ lae. Ẹnìkan ninu ìdílé rẹ tí n kò ní mú kúrò ní ibi pẹpẹ mi, yóo sọkún títí tí ojú rẹ̀ yóo fi di bàìbàì, ọkàn rẹ̀ yóo sì kún fún ìbànújẹ́. Gbogbo ọmọ inú ilé rẹ ni wọn yóo fi idà pa ní ọjọ́ àìpé. Ní ọjọ́ kan náà ni àwọn ọmọ rẹ mejeeji, Hofini ati Finehasi, yóo kú. Èyí ni yóo jẹ́ àmì fún ọ pé gbogbo ohun tí mo sọ ni yóo ṣẹ. N óo yan alufaa mìíràn fún ara mi, tí yóo ṣe olóòótọ́ sí mi, tí yóo sì ṣe gbogbo ohun tí mo bá fẹ́ kí ó ṣe. N óo fi ìdí ìdílé rẹ̀ múlẹ̀, yóo sì máa ṣe iṣẹ́ alufaa níwájú ẹni àmì òróró mi. Èyíkéyìí tí ó bá wà láàyè ninu arọmọdọmọ rẹ yóo máa tọ alufaa yìí lọ láti tọrọ owó ati oúnjẹ lọ́wọ́ rẹ̀. Ẹ̀bẹ̀ ni yóo sì máa bẹ̀, pé kí ó fi òun sí ipò alufaa kí òun baà lè máa rí oúnjẹ jẹ.” Ní gbogbo àkókò tí Samuẹli wà ní ọmọde, tí ó ń ṣiṣẹ́ fún OLUWA lábẹ́ Eli, OLUWA kò fi bẹ́ẹ̀ bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀ mọ́, kò sì fi bẹ́ẹ̀ sí ìran rírí láti ọ̀dọ̀ OLUWA mọ́. Ní àkókò yìí, ojú Eli ti di bàìbàì, kò ríran dáradára mọ́. Òun sùn sinu yàrá tirẹ̀, ṣugbọn Samuẹli sùn ninu ilé OLUWA, níbi tí àpótí Ọlọrun wà. Iná fìtílà ibi mímọ́ kò tíì jó tán. OLUWA bá pe Samuẹli, ó ní, “Samuẹli! Samuẹli!” Samuẹli dáhùn pé, “Èmi nìyí.” Ó bá dìde, ó sáré tọ Eli lọ, ó ní, “Ìwọ ni o pè mí; mo dé.” Ṣugbọn Eli dá a lóhùn pé, “N kò pè ọ́, pada lọ sùn.” Samuẹli bá pada lọ sùn. OLUWA tún pe Samuẹli. Samuẹli dìde, ó tún tọ Eli lọ, ó ní, “Ìwọ ni o pè mí; mo dé.” Eli tún dá a lóhùn pé, “N kò pè ọ́, ọmọ mi, pada lọ sùn.” Samuẹli kò mọ̀ pé OLUWA ni, nítorí OLUWA kò tíì bá a sọ̀rọ̀ rí. OLUWA pe Samuẹli nígbà kẹta, ó bá tún dìde, ó tọ Eli lọ, ó ní “Ìwọ ni o pè mí; mo dé.” Eli wá mọ̀ nígbà náà pé, OLUWA ni ó ń pe ọmọ náà. Ó bá wí fún un pé, “Pada lọ sùn. Bí olúwarẹ̀ bá tún pè ọ́, dá a lóhùn pé, ‘Máa wí OLUWA, iranṣẹ rẹ ń gbọ́.’ ” Samuẹli bá pada lọ sùn. OLUWA tún wá, ó dúró níbẹ̀, ó pe Samuẹli bí ó ti pè é tẹ́lẹ̀, ó ní “Samuẹli! Samuẹli!” Samuẹli bá dáhùn pé, “Máa wí, OLUWA, iranṣẹ rẹ ń gbọ́.” OLUWA bá sọ fún un pé, “Mo múra tán láti ṣe nǹkankan ní Israẹli, ohun tí mo fẹ́ ṣe náà yóo burú tóbẹ́ẹ̀ tí yóo ya ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ lẹ́nu. Ní ọjọ́ náà, n óo ṣe gbogbo ohun tí mo ti sọ pé n óo ṣe sí ìdílé Eli, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin. Mo ti sọ fún un pé n óo jẹ ìdílé rẹ̀ níyà títí lae, nítorí pé àwọn ọmọ rẹ̀ ti ṣe nǹkan burúkú sí mi. Eli mọ̀ pé wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ ṣugbọn kò dá wọn lẹ́kun. Nítorí náà, mo ti búra fún ilé Eli pé, kò sí ẹbọ kan tabi ọrẹ tí ó lè wẹ ẹ̀ṣẹ̀ burúkú náà kúrò laelae.” Samuẹli dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀ títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji. Nígbà tí ó di òwúrọ̀, ó dìde, ó ṣí gbogbo ìlẹ̀kùn ilé OLUWA, ṣugbọn ẹ̀rù ń bà á láti sọ ìran tí ó rí fún Eli. Eli pè é, ó ní, “Samuẹli, ọmọ mi!” Samuẹli dá a lóhùn pé, “Èmi nìyí.” Eli bi í pé, “Kí ni OLUWA wí fún ọ, má fi nǹkankan pamọ́ fún mi. OLUWA yóo ṣe sí ọ jù bí ó ti sọ fún ọ lọ, bí o bá fi nǹkankan pamọ́ fún mi ninu ohun tí ó sọ fún ọ.” Samuẹli bá sọ gbogbo rẹ̀ patapata, kò fi nǹkankan pamọ́ fún un. Eli dáhùn pé, “OLUWA ni, jẹ́ kí ó ṣe bí ó bá ti tọ́ lójú rẹ̀.” Samuẹli sì ń dàgbà, OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ó sì ń mú kí gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa ṣẹ. Gbogbo Israẹli láti Dani dé Beeriṣeba, ni wọ́n mọ̀ pé wolii OLUWA ni Samuẹli nítòótọ́. OLUWA tún fi ara hàn ní Ṣilo, nítorí pé níbẹ̀ ni ó ti kọ́ fi ara han Samuẹli, tí ó sì bá a sọ̀rọ̀. Ní àkókò náà, àwọn ará Filistia kó ara wọn jọ láti gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli, àwọn ọmọ Israẹli náà bá kó ogun jáde láti bá wọn jà. Àwọn ọmọ ogun Israẹli pàgọ́ sí Ebeneseri, àwọn ọmọ ogun Filistini sì pa tiwọn sí Afeki. Àwọn ọmọ ogun Filistini ni wọ́n kọ́ kọlu àwọn ọmọ ogun Israẹli, nígbà tí àwọn mejeeji gbógun pàdé ara wọn, tí wọ́n sì jà fitafita; àwọn ọmọ ogun Filistini ṣẹgun Israẹli, wọ́n sì pa nǹkan bíi ẹgbaaji (4,000) ninu wọn. Nígbà tí wọ́n pada dé ibùdó, àwọn àgbààgbà Israẹli bèèrè pé, “Kí ló dé tí OLUWA fi jẹ́ kí àwọn ará Filistia ṣẹgun wa lónìí? Ẹ jẹ́ kí á lọ gbé àpótí ẹ̀rí tí ó wà ní Ṣilo wá sọ́dọ̀ wa, kí ó lè máa bá wa lọ, kí ó sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa.” Wọ́n bá ranṣẹ lọ sí Ṣilo láti gbé àpótí ẹ̀rí OLUWA tí ó gúnwà láàrin àwọn Kerubu. Àwọn ọmọ Eli mejeeji, Hofini ati Finehasi, sì tẹ̀lé àpótí ẹ̀rí náà. Nígbà tí wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí dé ibùdó, gbogbo Israẹli hó ìhó ayọ̀, tóbẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ mì tìtì. Nígbà tí àwọn ará Filistia gbọ́ híhó tí wọn ń hó, wọ́n ní, “Irú ariwo ńlá wo ni àwọn Heberu ń pa ní ibùdó wọn yìí?” Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé àpótí ẹ̀rí OLUWA ni ó dé sí ibùdó àwọn Heberu, ẹ̀rù ba àwọn ará Filistia. Wọ́n ní, “Oriṣa kan ti dé sí ibùdó wọn! A gbé! Irú èyí kò ṣẹlẹ̀ rí. A gbé! Ta ni lè gbà wá lọ́wọ́ àwọn oriṣa tí ó lágbára wọnyi? Àwọn ni wọ́n pa àwọn ará Ijipti ní ìpakúpa ninu aṣálẹ̀. Ẹ ṣe ọkàn yín gírí, ẹ̀yin ọmọ ogun Filistini! Ẹ ṣe bí akọni, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a óo di ẹrú àwọn ará Heberu gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti jẹ́ ẹrú wa, nítorí náà, ẹ ṣe bí akọni, kí ẹ sì jà.” Àwọn ọmọ ogun Filistini jà fitafita, wọ́n ṣẹgun Israẹli, olukuluku àwọn ọmọ Israẹli sì sá pada lọ sí ilé rẹ̀, ọpọlọpọ ló kú ninu wọn. Ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaarun (30,000) ni ọmọ ogun Filistini pa ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli tí ń fi ẹsẹ̀ rìn. Wọ́n gba àpótí ẹ̀rí Ọlọrun lọ́wọ́ àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì pa Hofini ati Finehasi, àwọn ọmọ Eli mejeeji. Ọkunrin kan láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, ti ojú ogun sáré pada lọ sí Ṣilo, ó sì dé ibẹ̀ lọ́jọ́ náà. Ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì ku erùpẹ̀ sórí láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn. Ọkàn Eli dàrú gidigidi nítorí àpótí ẹ̀rí náà, ó sì jókòó lórí àga rẹ̀ lẹ́bàá ọ̀nà, ó ń wo òréré. Ọkunrin tí ó ti ojú ogun wá bẹ̀rẹ̀ sí ròyìn fún àwọn ará ìlú, ẹ̀rù ba olukuluku, àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí ké. Nígbà tí Eli gbọ́ igbe wọn, ó bèèrè pé, “Kí ni wọ́n ń kígbe báyìí fún?” Ọkunrin náà bá yára wá sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Eli. Eli ti di ẹni ọdún mejidinlọgọrun-un ní àkókò yìí, ojú rẹ̀ sì fẹ́rẹ̀ má ríran mọ́ rárá. Ọkunrin náà wí fún un pé, “Ojú ogun ni mo ti sá wá lónìí.” Eli bá bi í pé, “Kí ló dé, ọmọ mi?” Ọkunrin náà dáhùn pé, “Israẹli sá níwájú àwọn ará Filistia. Wọ́n pa ọpọlọpọ ninu wa, wọ́n pa Hofini ati Finehasi, àwọn ọmọ rẹ mejeeji pẹlu. Wọ́n sì gbé àpótí Ọlọrun lọ.” Nígbà tí ọkunrin náà fẹnu kan àpótí Ọlọ́run, Eli ṣubú sẹ́yìn lórí àpótí tí ó jókòó lé ní ẹnu ọ̀nà, ọrùn rẹ̀ ṣẹ́, ó sì kú, nítorí pé ó ti di arúgbó, ó sì sanra. Ogoji ọdún ni Eli fi ṣe adájọ́ ní ilẹ̀ Israẹli. Iyawo Finehasi, ọmọ Eli, wà ninu oyún ní àkókò náà, ọjọ́ ìkúnlẹ̀ rẹ̀ sì ti súnmọ́ etílé. Nígbà tí ó gbọ́ pé wọ́n ti gbé àpótí Ọlọrun lọ, ati pé baba ọkọ rẹ̀ ati ọkọ rẹ̀ ti kú, lẹsẹkẹsẹ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí rọbí, tí ó sì bímọ. Bí ó ti ń kú lọ, àwọn obinrin tí wọn ń gbẹ̀bí rẹ̀ wí fún un pé, “Ṣe ọkàn gírí, ọkunrin ni ọmọ tí o bí.” Ṣugbọn kò tilẹ̀ kọ ibi ara sí ohun tí wọ́n sọ, kò sì dá wọn lóhùn. Ó bá sọ ọmọ náà ní Ikabodu, ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, “Ògo Ọlọrun ti fi Israẹli sílẹ̀.” Nítorí pé wọ́n ti gba àpótí Ọlọrun ati pé baba ọkọ rẹ̀ ati ọkọ rẹ̀ ti kú. Ó ní, “Ògo Ọlọrun ti fi Israẹli sílẹ̀, nítorí pé wọ́n ti gbé àpótí Ọlọrun lọ.” Lẹ́yìn tí àwọn ará Filistia gba àpótí Ọlọrun lọ́wọ́ àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n gbé e láti Ebeneseri lọ sí Aṣidodu. Wọ́n gbé e lọ sí ilé Dagoni, oriṣa wọn; wọ́n sì gbé e kalẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ère oriṣa náà. Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, àwọn ará ìlú Aṣidodu rí i pé ère Dagoni ti ṣubú lulẹ̀. Wọ́n bá a tí ó dojúbolẹ̀ níwájú àpótí OLUWA. Wọ́n bá gbé e dìde, wọ́n gbé e pada sí ààyè rẹ̀. Nígbà tí ó tún di òwúrọ̀ kutukutu wọ́n tún bá a tí ère náà tún ti ṣubú tí ó tún ti dojú bolẹ̀ níwájú àpótí OLUWA, ati pé orí ati ọwọ́ rẹ̀ mejeeji ti gé kúrò, wọ́n wà nílẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà, ara rẹ̀ nìkan ni ó kù. Ìdí nìyí tí ó fi jẹ́ pé títí di òní olónìí, àwọn babalóòṣà oriṣa Dagoni ati gbogbo àwọn tí wọ́n máa ń bọ ọ́ kò jẹ́ tẹ ẹnu ọ̀nà ilé oriṣa Dagoni tí ó wà ní ìlú Aṣidodu, dídá ni wọ́n máa ń dá a kọjá. OLUWA jẹ àwọn ará ìlú Aṣidodu níyà gidigidi, ó sì dẹ́rùbà wọ́n. Ìyà tí ó fi jẹ wọ́n, ati àwọn tí wọn ń gbé agbègbè wọn ni pé gbogbo ara wọn kún fún kókó ọlọ́yún. Nígbà tí àwọn ará Aṣidodu rí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀, wọ́n ní, “Ọlọrun Israẹli ni ó ń jẹ àwa ati Dagoni, oriṣa wa níyà. A kò lè jẹ́ kí àpótí Ọlọrun Israẹli yìí wà lọ́dọ̀ wa níhìn-ín mọ́ rárá.” Wọ́n bá ranṣẹ lọ pe àwọn ọba Filistini jọ, wọ́n sì bi wọ́n pé, “Báwo ni kí á ti ṣe àpótí Ọlọrun Israẹli yìí?” Wọ́n dáhùn pé kí wọ́n gbé e lọ sí Gati; wọ́n bá gbé e lọ sibẹ. Ṣugbọn nígbà tí àpótí Ọlọrun náà dé Gati, OLUWA jẹ ìlú náà níyà, ó mú kí gbogbo ara wọn kún fún kókó ọlọ́yún ati àgbà ati èwe wọn, ó sì mú ìpayà bá gbogbo wọn. Wọ́n tún gbé àpótí Ọlọrun náà ranṣẹ sí ìlú Filistini mìíràn, tí wọn ń pè ní Ekironi. Ṣugbọn bí wọ́n ti gbé e dé Ekironi ni àwọn ará ìlú fi igbe ta pé, “Wọ́n ti gbé àpótí Ọlọrun Israẹli dé síhìn-ín, láti pa gbogbo wa run.” Wọ́n bá ranṣẹ pe àwọn ọba Filistini, wọ́n wí fún wọn pé, “Ẹ gbé àpótí Ọlọrun Israẹli pada sí ibi tí ẹ ti gbé e wá, kí ó má baà pa àwa ati ìdílé wá run.” Ìpayà ńlá ti bá gbogbo ìlú nítorí OLUWA ń jẹ wọ́n níyà gidigidi. Ara gbogbo àwọn tí kò kú ninu wọn kún fún kókó ọlọ́yún. Ariwo àwọn eniyan náà sì pọ̀ pupọ. Lẹ́yìn tí àpótí OLUWA ti wà ní ilẹ̀ Filistini fún oṣù meje, àwọn ará ilẹ̀ náà pe àwọn babalóòṣà wọn ati àwọn adáhunṣe wọn jọ, wọ́n bi wọ́n pé, “Báwo ni kí á ti ṣe àpótí OLUWA? Bí a óo bá dá a pada sí ibi tí wọ́n ti gbé e wá, kí ni kí á fi ranṣẹ pẹlu rẹ̀?” Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Bí ẹ óo bá dá àpótí Ọlọrun Israẹli pada, ẹ gbọdọ̀ dá a pada pẹlu ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, àpótí ẹ̀rí náà kò gbọdọ̀ pada lọ lásán, láìsí nǹkan ètùtù. Bẹ́ẹ̀ ni ara yín yóo ṣe yá, ẹ óo sì mọ ìdí tí Ọlọrun fi ń jẹ yín níyà.” Àwọn eniyan náà bi wọ́n pé, “Kí ni kí á fi ranṣẹ gẹ́gẹ́ bí nǹkan ètùtù?” Àwọn babalóòṣà dá wọn lóhùn pé, “Ẹ fi wúrà yá ère kókó ọlọ́yún marun-un, ati ti èkúté marun-un, kí ẹ fi ranṣẹ. Kókó ọlọ́yún wúrà marun-un ati èkúté marun-un dúró fún àwọn ọba Filistini maraarun. Nítorí àjàkálẹ̀ àrùn kan náà ni ó kọlu gbogbo yín ati àwọn ọba yín maraarun. Ẹ gbọdọ̀ fi wúrà yá ère kókó ọlọ́yún yín ati ti èkúté tí ń ba ilẹ̀ yín jẹ́, kí ẹ sì fi ògo fún Ọlọrun Israẹli bóyá ó lè dáwọ́ ìjìyà rẹ̀ dúró lórí ẹ̀yin ati oriṣa yín, ati ilẹ̀ yín. Kí ló dé tí ẹ fi fẹ́ ṣe oríkunkun, bí ọba ilẹ̀ Ijipti ati àwọn ará Ijipti. Ẹ ranti bí Ọlọrun ti fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà títí tí wọ́n fi jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli lọ. Wọ́n kúkú lọ! Nítorí náà ẹ kan kẹ̀kẹ́ ẹrù tuntun kan, kí ẹ sì tọ́jú abo mààlúù meji tí ń fún ọmọ lọ́mú tí ẹnikẹ́ni kò sì so àjàgà mọ́ lọ́rùn rí, ẹ so kẹ̀kẹ́ ẹrù náà mọ́ wọn lọ́rùn, kí ẹ sì lé àwọn ọmọ wọn pada sílé. Ẹ gbé àpótí OLUWA lé orí kẹ̀kẹ́ ẹrù náà. Ẹ kó àwọn kókó ọlọ́yún ati àwọn èkúté tí ẹ fi wúrà ṣe, tí ẹ fẹ́ fi ranṣẹ gẹ́gẹ́ bí nǹkan ètùtù sinu àpótí kan, kí ẹ wá gbé e sí ẹ̀gbẹ́ àpótí OLUWA. Lẹ́yìn náà, ẹ ti kẹ̀kẹ́ ẹrù yìí sójú ọ̀nà, kí ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ fúnrarẹ̀. Ẹ máa kíyèsí i bí ó bá ti ń lọ. Bí ó bá doríkọ ọ̀nà ìlú Beti Ṣemeṣi, a jẹ́ pé Ọlọrun àwọn ọmọ Israẹli ni ó kó gbogbo àjálù yìí bá wa. Bí kò bá doríkọ ibẹ̀, a óo mọ̀ pé kì í ṣe òun ló rán àjálù náà sí wa, a jẹ́ pé ó kàn dé bá wa ni.” Àwọn eniyan náà ṣe bí àwọn babalóòṣà ti wí. Wọ́n mú mààlúù meji tí wọn ń fún ọmọ lọ́mú lọ́wọ́, wọ́n so kẹ̀kẹ́ ẹrù náà mọ́ wọn lọ́rùn, wọ́n sì ti àwọn ọmọ wọn mọ́lé. Wọ́n gbé àpótí OLUWA sinu kẹ̀kẹ́ ẹrù náà, pẹlu àpótí tí wọ́n kó àwọn èkúté wúrà ati kókó ọlọ́yún wúrà náà sí. Àwọn mààlúù yìí bá doríkọ ọ̀nà Beti Ṣemeṣi, wọ́n ń lọ tààrà láì yà sọ́tùn-ún tabi sósì. Wọ́n ń ké bí wọ́n ti ń lọ. Àwọn ọba Filistini maraarun tẹ̀lé wọn títí dé odi Beti Ṣemeṣi. Àwọn ará ìlú Beti ṣemeṣi ń kórè ọkà lọ́wọ́ ní àfonífojì náà, bí wọ́n ti gbójú sókè, wọ́n rí àpótí ẹ̀rí. Inú wọn dùn pupọ pupọ bí wọ́n ti rí i. Nígbà tí kẹ̀kẹ́ ẹrù náà dé ibi oko Joṣua, ará Beti Ṣemeṣi, ó dúró níbẹ̀. Àpáta ńlá kan wà níbẹ̀, àwọn eniyan náà bá gé igi tí wọ́n fi kan kẹ̀kẹ́ ẹrù náà sí wẹ́wẹ́, wọ́n pa mààlúù mejeeji, wọ́n sì fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA. Àwọn ọmọ Lefi bá gbé àpótí OLUWA náà, ati àpótí tí àwọn ohun tí wọ́n fi wúrà ṣe wà, wọ́n gbé wọn ka orí àpáta ńlá náà. Lẹ́yìn náà, àwọn ará ìlú Beti Ṣemeṣi rú ẹbọ sísun, ati oríṣìíríṣìí ẹbọ mìíràn sí OLUWA ní ọjọ́ náà. Àwọn ọba Filistini ń wò wọ́n bí wọ́n ti ń ṣe, lẹ́yìn náà, wọ́n yipada sí ìlú Ekironi ní ọjọ́ náà gan-an. Àwọn ará Filistia fi kókó ọlọ́yún marun-un náà tí wọ́n fi wúrà ṣe ranṣẹ gẹ́gẹ́ bí nǹkan ètùtù. Ọ̀kọ̀ọ̀kan fún ìlú kọ̀ọ̀kan; Aṣidodu, Gasa, Aṣikeloni, Gati ati Ekironi. Wọ́n sì fi àwọn èkúté marun-un tí wọ́n fi wúrà ṣe ranṣẹ. Èkúté kọ̀ọ̀kan dúró fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu ìlú àwọn ọba Filistini maraarun. Àwọn maraarun wà fún àwọn ìlú olódi àwọn ọba Filistini, pẹlu àwọn ìletò kéékèèké wọn, tí kò ní odi. Àpáta ńlá tí ó wà ninu oko Joṣua ará Beti Ṣemeṣi, tí àwọn ọmọ Lefi gbé àpótí OLUWA náà lé wà níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ títí di òní olónìí. Aadọrin ninu àwọn ará ìlú Beti Ṣemeṣi ni OLUWA pa, nítorí pé, wọ́n yọjú wo inú àpótí OLUWA náà. Àwọn eniyan náà sì ṣọ̀fọ̀ nítorí pé OLUWA pa ọpọlọpọ ninu wọn. Àwọn ará ìlú Beti Ṣemeṣi ní, “Ta ló lè dúró níwájú OLUWA Ọlọrun mímọ́ yìí? Ọ̀dọ̀ ta ni yóo fẹ́ lọ, tí yóo fi kúrò lọ́dọ̀ wa?” Wọ́n bá ranṣẹ sí àwọn ará ìlú Kiriati Jearimu pé, “Àwọn ará Filistia ti dá àpótí OLUWA pada. Ẹ wá gbé e.” Àwọn ará ìlú Kiriati Jearimu wá, wọ́n gbé àpótí OLUWA náà lọ sí ilé Abinadabu, tí ń gbé orí òkè kan. Wọ́n ya Eleasari, ọmọ rẹ̀ sí mímọ́, láti máa bojútó àpótí OLUWA náà. Láti ìgbà náà, Kiriati Jearimu ni wọ́n gbé àpótí OLUWA sí fún nǹkan bíi ogún ọdún, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì ń ké pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́. Samuẹli bá sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Bí ẹ bá fẹ́ pada sọ́dọ̀ OLUWA tọkàntọkàn, ẹ gbọdọ̀ kó gbogbo oriṣa ati gbogbo ère oriṣa Aṣitarotu, tí ó wà lọ́dọ̀ yín dànù; ẹ palẹ̀ ọkàn yín mọ́ fún OLUWA, kí ẹ sì máa sin òun nìkan ṣoṣo; yóo sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ará Filistia.” Àwọn ọmọ Israẹli bá kó gbogbo oriṣa Baali ati ti Aṣitarotu wọn dànù, wọ́n sì ń sin OLUWA nìkan. Samuẹli ní kí wọ́n kó gbogbo eniyan Israẹli jọ sí Misipa, ó ní òun óo gbadura sí OLUWA fún wọn níbẹ̀. Gbogbo wọn bá péjọ sí Misipa, wọ́n pọn omi, wọ́n dà á sílẹ̀, wọ́n sì ṣe ètùtù níwájú OLUWA. Wọ́n gbààwẹ̀ ṣúlẹ̀ ọjọ́ náà, wọ́n ní, “A ti ṣẹ̀ sí OLUWA.” Samuẹli sì ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan Israẹli ní Misipa. Nígbà tí àwọn ará Filistia gbọ́ pé àwọn ọmọ Israẹli péjọ sí Misipa, àwọn ọba Filistini kó àwọn eniyan wọn jọ láti gbógun tì wọ́n. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbọ́, ẹ̀rù bà wọ́n. Wọ́n bá wí fún Samuẹli pé, “Má dákẹ́, gbadura sí OLUWA Ọlọrun wa, kí ó gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Filistia.” Samuẹli pa ọmọ aguntan kan tí ó ṣì ń mu ọmú, ó sun ún lódidi, ó fi rúbọ sí OLUWA. Lẹ́yìn náà, ó gbadura sí OLUWA fún ìrànlọ́wọ́ Israẹli; OLUWA sì gbọ́ adura rẹ̀. Nígbà tí Samuẹli ń rúbọ lọ́wọ́, àwọn ará Filistia ń súnmọ́ ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli, láti bá wọn jagun. Ṣugbọn OLUWA sán ààrá lù wọ́n láti ọ̀run wá. Ìdààmú bá wọn, wọ́n sì túká pẹlu ìpayà. Àwọn ọmọ Israẹli bá kó ogun jáde láti Misipa, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn ọmọ ogun Filistini lọ títí wọ́n fi fẹ́rẹ̀ dé ìsàlẹ̀ Betikari, wọ́n ń pa wọ́n bí wọ́n ti ń lé wọn lọ. Samuẹli gbé òkúta kan, ó rì í mọ́lẹ̀ láàrin Misipa ati Ṣeni, ó sì sọ ibẹ̀ ni Ebeneseri, ó ní, “OLUWA ràn wá lọ́wọ́ títí dé ìhín yìí.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan Israẹli ṣe ṣẹgun àwọn ará Filistia, wọn kò sì gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli mọ́. OLUWA n ṣe àwọn ará Filistia níbi ní gbogbo ọjọ́ ayé Samuẹli. Gbogbo ìlú tí àwọn Filistini ti gbà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Israẹli, láti Ekironi títí dé Gati, ni wọ́n dá pada fún wọn. Àwọn ọmọ Israẹli gba gbogbo ilẹ̀ wọn pada lọ́wọ́ àwọn ará Filistia. Alaafia wà láàrin àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn ará Amori. Samuẹli jẹ́ adájọ́ ní ilẹ̀ Israẹli títí tí ó fi kú. Lọdọọdun níí máa ń lọ yípo Bẹtẹli, Giligali, ati Misipa, láti ṣe ìdájọ́. Lẹ́yìn náà, yóo pada lọ sí ilé rẹ̀, ní Rama, nítorí pé a máa dájọ́ fún àwọn eniyan níbẹ̀ pẹlu. Ó sì tẹ́ pẹpẹ kan sibẹ fún OLUWA. Nígbà tí àgbà dé sí Samuẹli, ó fi àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe adájọ́ ní ilẹ̀ Israẹli. Joẹli ni orúkọ àkọ́bí, èyí àbúrò sì ń jẹ́ Abija. Beeriṣeba ni wọ́n ti ń ṣe adájọ́. Ṣugbọn wọn kò tẹ̀lé àpẹẹrẹ rere baba wọn. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ owó, wọ́n ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì ń dájọ́ èké. Gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli bá kó ara wọn jọ, wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ Samuẹli ní Rama; wọ́n wí fún un pé, “Wò ó, àgbà ti dé sí ọ, àwọn ọmọ rẹ kò sì tẹ̀lé àpẹẹrẹ rere rẹ. Yan ẹnìkan, gẹ́gẹ́ bí ọba fún wa, tí yóo máa ṣe alákòóso wa bí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.” Ọ̀rọ̀ náà kò dùn mọ́ Samuẹli ninu, pé àwọn eniyan náà ní kí ó fi ẹnìkan jọba lórí wọn. Samuẹli bá gbadura sí OLUWA. OLUWA dá Samuẹli lóhùn, ó ní, “Gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn eniyan náà wí fún ọ, nítorí pé kì í ṣe ìwọ ni wọ́n kọ̀, èmi ni wọ́n kọ̀ lọ́ba. Láti ìgbà tí mo ti kó wọn wá láti Ijipti títí di òní ni wọ́n ti kọ̀yìn sí mi, tí wọ́n sì ń bọ oriṣa. Ohun tí wọ́n ti ń ṣe sí mi ni wọ́n ń ṣe sí ọ yìí. Nítorí náà, gbọ́ tiwọn, ṣugbọn kìlọ̀ fún wọn gidigidi, kí o sì ṣe àlàyé gbogbo ohun tí ọba náà yóo máa ṣe sí wọn fún wọn dáradára.” Samuẹli bá sọ gbogbo ohun tí OLUWA bá a sọ fún àwọn tí wọ́n ní kí ó fi ẹnìkan jọba lórí àwọn. Ó ṣe àlàyé fún wọn pé, “Bí ọba yín yóo ti máa ṣe yín nìyí: Yóo sọ àwọn ọmọkunrin yín di ọmọ ogun, àwọn kan ninu wọn yóo máa wa kẹ̀kẹ́ ogun, àwọn kan yóo wà ninu ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ń fi ẹsẹ̀ rìn, àwọn kan yóo máa gun ẹṣin níwájú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀. Yóo fi àwọn kan ṣe ọ̀gágun fún ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun, àwọn kan yóo máa ṣe ọ̀gágun fún araadọta ọmọ ogun. Àwọn kan yóo máa ro oko rẹ̀, àwọn kan yóo sì máa kórè àwọn ohun ọ̀gbìn rẹ̀. Àwọn kan yóo máa rọ ohun ìjà fún un, ati àwọn ohun èlò kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀. Àwọn ọmọbinrin yín ni yóo máa ṣe turari fún un, wọn óo sì máa se oúnjẹ fún un. Yóo gba ilẹ̀ oko yín tí ó dára jùlọ ati ọgbà àjàrà ati ti olifi yín, yóo sì fi fún àwọn iranṣẹ rẹ̀. Yóo gba ìdámẹ́wàá ọkà yín ati ti ọgbà àjàrà yín fún àwọn ẹmẹ̀wà ati àwọn iranṣẹ rẹ̀. Yóo gba àwọn iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin yín, ati àwọn mààlúù ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yín tí wọ́n dára jùlọ, yóo máa kó wọn ṣiṣẹ́. Yóo gba ìdámẹ́wàá agbo aguntan yín, ẹ̀yin gan-an yóo sì di ẹrú rẹ̀. Nígbà tí ó bá yá, ẹ̀yin gan-an ni ẹ óo tún máa pariwo ọba yín tí ẹ yàn fún ara yín, ṣugbọn OLUWA kò ní da yín lóhùn.” Ṣugbọn àwọn eniyan náà kọ̀, wọn kò gba ohun tí Samuẹli wí gbọ́. Wọ́n ní, “Rárá o! A ṣá fẹ́ ní ọba ni. Kí àwa náà lè dàbí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, kí ọba wa lè máa ṣe àkóso wa, kí ó máa ṣiwaju wa lójú ogun, kí ó sì máa jà fún wa.” Nígbà tí Samuẹli gbọ́ gbogbo ohun tí wọ́n wí, ó lọ sọ fún OLUWA. OLUWA sọ fún Samuẹli pé, “Ṣe ohun tí wọ́n fẹ́, kí o sì yan ọba fún wọn.” Samuẹli bá sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí olukuluku pada lọ sí ìlú rẹ̀. Ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan wà, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kiṣi, ọmọ Abieli, ọmọ Serori, ọmọ Bekorati, ọmọ Afaya láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini. Ó ní ọmọkunrin kan tí ń jẹ́ Saulu. Saulu yìí jẹ́ arẹwà ọkunrin. Láti èjìká rẹ̀ sókè ni ó fi ga ju ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli lọ, ó sì lẹ́wà ju ẹnikẹ́ni ninu wọn lọ. Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Kiṣi, baba Saulu sọnù. Kiṣi bá sọ fún Saulu ọmọ rẹ̀ pé, “Mú ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ lẹ́yìn, kí ẹ lọ wá àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà wá.” Wọ́n wá gbogbo agbègbè olókè Efuraimu káàkiri, ati gbogbo agbègbè Ṣaliṣa, ṣugbọn wọn kò rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà. Wọ́n wá gbogbo agbègbè Ṣaalimu, ṣugbọn wọn kò rí wọn níbẹ̀. Lẹ́yìn náà wọ́n wá gbogbo ilẹ̀ Bẹnjamini, sibẹsibẹ wọn kò rí wọn. Nígbà tí wọ́n dé agbègbè Sufu, Saulu sọ fún iranṣẹ tí ó wà pẹlu rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí á pada sílé, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, baba mi lè má ronú nípa àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mọ́, kí ó máa páyà nítorí tiwa.” Iranṣẹ náà dá a lóhùn, ó ní, “Dúró ná, eniyan Ọlọrun kan wà ní ilẹ̀ yìí, tí gbogbo eniyan ń bu ọlá fún, nítorí pé gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ níí máa ń ṣẹ. Jẹ́ kí á lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, bóyá ó lè sọ ibi tí a óo ti rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà fún wa.” Saulu dá a lóhùn pé, “Bí a bá tọ eniyan Ọlọrun yìí lọ nisinsinyii, kí ni a óo mú lọ́wọ́ lọ fún un? Oúnjẹ tí ó wà ninu àpò wa ti tán, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí nǹkankan lọ́wọ́ wa tí a lè fún un. Àbí kí ni a óo fún un?” Iranṣẹ náà dá Saulu lóhùn, ó ní, “Mo ní idamẹrin owó ṣekeli fadaka kan lọ́wọ́, n óo fún un, yóo sì sọ ibi tí a óo ti rí wọn fún wa.” (Ní àtijọ́, ní ilẹ̀ Israẹli, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ Ọlọrun, yóo wí pé, òun ń lọ sí ọ̀dọ̀ aríran; nítorí àwọn tí àwa ń pè ní wolii lónìí, aríran ni wọ́n ń pè wọ́n nígbà náà.) Saulu bá dá a lóhùn pé, “O ṣeun, jẹ́ kí á lọ.” Wọ́n bá lọ sí ìlú tí eniyan Ọlọrun yìí wà. Bí wọ́n ti ń gun òkè lọ láti wọ ìlú, wọ́n pàdé àwọn ọmọbinrin tí wọ́n ń jáde lọ pọn omi. Wọ́n bi àwọn ọmọbinrin náà pé, “Ǹjẹ́ aríran wà ní ìlú?” Àwọn ọmọbinrin náà dá wọn lóhùn pé, “Ó wà ní ìlú. Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọjá nisinsinyii ni. Bí ó ti ń wọ ìlú bọ̀ tààrà nìyí, ẹ yára lọ bá a. Àwọn eniyan ní ẹbọ kan tí wọn óo rú ní orí òkè lónìí. Bí ẹ bá tí ń wọ ìlú ni ẹ óo rí i. Ẹ yára kí ẹ lè bá a, kí ó tó lọ sí orí òkè lọ jẹun; nítorí pé àwọn eniyan kò ní bẹ̀rẹ̀ sí jẹun títí tí yóo fi dé. Òun ni ó gbọdọ̀ súre sí ẹbọ náà, kí àwọn tí wọ́n bá pè tó bẹ̀rẹ̀ sí jẹun. Ẹ tètè máa lọ, ẹ óo bá a.” Saulu ati iranṣẹ rẹ̀ bá gòkè wọ ìlú lọ. Bí wọ́n ti ń lọ, wọ́n rí Samuẹli tí ń jáde bọ̀ wá sí ọ̀nà ọ̀dọ̀ wọn, ó ń lọ sí orí òkè tí wọ́n ti ń rúbọ. Ó ku ọ̀la kí Saulu dé ni OLUWA ti sọ fún Samuẹli pé, “Ní ìwòyí ọ̀la, n óo rán ọkunrin kan sí ọ láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini. O óo ta òróró sí i lórí láti yàn án ní ọba Israẹli, àwọn eniyan mi. Ọkunrin náà ni yóo gbà wọ́n kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Filistia, nítorí mo ti rí àwọn eniyan mi tí ń jìyà, mo sì ti gbọ́ igbe wọn.” Nígbà tí Samuẹli fi ojú kan Saulu, OLUWA wí fún un pé, “Ọkunrin tí mo sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún ọ nìyí. Òun ni yóo jọba lórí àwọn eniyan mi.” Saulu tọ Samuẹli lọ, lẹ́nu ibodè, ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Jọ̀wọ́, níbo ni ilé aríran?” Samuẹli dá a lóhùn pé, “Èmi aríran náà nìyí. Ẹ máa lọ sí ibi tí wọ́n ti ń rú ẹbọ, nítorí ẹ óo bá mi jẹun lónìí. Bí ó bá di òwúrọ̀ ọ̀la, n óo jẹ́ kí ẹ lọ, n óo sì sọ gbogbo ohun tí ẹ fẹ́ mọ̀ fun yín. Nípa ti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí wọ́n sọnù láti ìjẹta, ẹ má da ara yín láàmú, wọ́n ti rí wọn. Ṣugbọn ta ni ẹni náà tí àwọn eniyan Israẹli ń fẹ́ tóbẹ́ẹ̀? Ṣebí ìwọ ati ìdílé baba rẹ ni.” Saulu dá a lóhùn, ó ní, “Inú ẹ̀yà Bẹnjamini tí ó kéré jù ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli ni mo ti wá, ati pé ìdílé baba mi ni ó rẹ̀yìn jùlọ ninu ẹ̀yà Bẹnjamini. Kí ló dé tí o fi ń bá mi sọ irú ọ̀rọ̀ yìí?” Samuẹli bá mú Saulu ati iranṣẹ rẹ̀ wọ inú gbọ̀ngàn ńlá lọ, ó fi wọ́n jókòó sí ààyè tí ó ṣe pataki jùlọ níbi tabili oúnjẹ tí wọ́n fi àwọn àlejò bí ọgbọ̀n jókòó sí. Ó sọ fún alásè pé kí ó gbé ẹran tí òun ní kí ó fi sọ́tọ̀ wá. Alásè náà bá gbé ẹsẹ̀ ati itan ẹran náà wá, ó gbé e kalẹ̀ níwájú Saulu. Samuẹli wí fún Saulu pé, “Wò ó, ohun tí a ti pèsè sílẹ̀ dè ọ́ ni wọ́n gbé ka iwájú rẹ yìí. Máa jẹ ẹ́, ìwọ ni a fi pamọ́ dè, pé kí o jẹ ẹ́ ní àkókò yìí pẹlu àwọn tí mo pè.” Saulu ati Samuẹli bá jọ jẹun pọ̀ ní ọjọ́ náà. Nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá sinu ìlú láti ibi ìrúbọ náà, wọ́n tẹ́ ibùsùn kan fún Saulu lórí òrùlé, ó sì sùn sibẹ. Nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́júmọ́, Samuẹli pe Saulu lórí òrùlé, ó ní, “Dìde kí n sìn ọ́ sọ́nà.” Saulu dìde, òun ati Samuẹli bá jáde sí òpópónà. Nígbà tí wọ́n dé ibi odi ìlú, Samuẹli wí fún Saulu pé, “Sọ fún iranṣẹ rẹ kí ó máa nìṣó níwájú dè wá.” Iranṣẹ náà bá bọ́ siwaju, ó ń lọ. Samuẹli sọ fún Saulu pé, “Dúró díẹ̀ níhìn-ín kí n sọ ohun tí Ọlọrun wí fún ọ.” Nígbà náà ni Samuẹli mú ìgò òróró olifi kan, ó tú u lé Saulu lórí. Ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu, ó sì wí fún un pé, “OLUWA fi àmì òróró yàn ọ́ ní olórí àwọn eniyan Israẹli. Ohun tí yóo sì jẹ́ àmì tí o óo fi mọ̀ pé OLUWA ló yàn ọ́ láti jọba lórí àwọn eniyan rẹ̀ nìyí: Nígbà tí o bá kúrò ní ọ̀dọ̀ mi lónìí, o óo pàdé àwọn ọkunrin meji kan lẹ́bàá ibojì Rakẹli, ní Selisa, ní agbègbè Bẹnjamini. Wọn yóo sọ fún ọ pé, ‘Wọ́n ti rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ẹ̀ ń wá. Nisinsinyii baba rẹ kò dààmú nítorí ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mọ́, ṣugbọn ó ń jáyà nítorí rẹ, ó ń wí pé, “Kí ni n óo ṣe nípa ọmọ mi.” ’ Nígbà tí o bá kúrò níbẹ̀, tí o sì ń lọ, o óo dé ibi igi oaku tí ó wà ní Tabori. O óo pàdé àwọn ọkunrin mẹta kan, tí wọ́n ń lọ rúbọ sí Ọlọrun ní Bẹtẹli. Ọ̀kan ninu wọn yóo fa ọ̀dọ́ ewúrẹ́ mẹta lọ́wọ́, ekeji yóo kó burẹdi mẹta lọ́wọ́, ẹkẹta yóo sì gbé ìgò aláwọ kan tí ó kún fún ọtí waini lọ́wọ́. Wọn yóo kí ọ, wọn yóo sì fún ọ ní meji ninu burẹdi náà, gbà wọ́n lọ́wọ́ wọn. Lẹ́yìn náà, lọ sí òkè Ọlọrun ní Gibea Elohimu, ní ibi tí ibùdó àwọn ọmọ ogun Filistini kan wà. Nígbà tí ó bá kù díẹ̀ kí ẹ dé ìlú náà, o óo pàdé ọ̀wọ́ àwọn wolii kan, tí wọn ń sọ̀kalẹ̀ bọ̀ láti ibi pẹpẹ tí ó wà ní orí òkè. Wọn yóo máa ta hapu, wọn yóo máa lu aro, wọn yóo máa fọn fèrè, wọn yóo máa tẹ dùùrù, wọn yóo sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀. Nígbà náà, ẹ̀mí OLUWA yóo bà lé ọ, o óo sì darapọ̀ mọ́ wọn, o óo sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀, o óo sì yàtọ̀ patapata sí bí o ti wà tẹ́lẹ̀. Nígbà tí gbogbo nǹkan wọnyi bá ṣẹlẹ̀ sí ọ, ṣe ohunkohun tí ó bá wá sọ́kàn rẹ, nítorí Ọlọrun wà pẹlu rẹ. Máa lọ sí Giligali ṣiwaju mi. N óo wá bá ọ níbẹ̀ láti rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia. Dúró níbẹ̀ fún ọjọ́ meje, títí tí n óo fi dé, n óo sì sọ ohun tí o óo ṣe fún ọ.” Yíyí tí Saulu yipada kúrò lọ́dọ̀ Samuẹli, Ọlọrun sọ ọ́ di ẹ̀dá titun. Gbogbo àwọn àmì tí Samuẹli sọ fún un patapata ni ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ náà. Nígbà tí Saulu ati iranṣẹ rẹ̀ dé Gibea, ọ̀wọ́ àwọn wolii kan pàdé rẹ̀. Ẹ̀mí Ọlọrun bà lé e, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀ láàrin wọn. Nígbà tí àwọn tí wọ́n ti mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀ rí i bí ó ti ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ pẹlu àwọn wolii, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè lọ́wọ́ ara wọn pé, “Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ọmọ Kiṣi? Àbí Saulu náà ti di wolii ni?” Ọkunrin kan tí ń gbé ibẹ̀ bèèrè pé, “Ta ni baba àwọn wolii wọnyi?” Láti ìgbà náà ni ó ti di àṣà kí àwọn eniyan máa wí pé, “Àbí Saulu náà ti di wolii ni?” Lẹ́yìn tí Saulu ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ tán, ó lọ sí ibi pẹpẹ, ní orí òkè. Arakunrin baba rẹ̀ rí òun ati iranṣẹ rẹ̀, ó bi wọ́n pé, “Níbo ni ẹ ti lọ?” Saulu dáhùn pé, “Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni a wá lọ. Nígbà tí a wá wọn tí a kò rí wọn, a lọ sọ́dọ̀ Samuẹli.” Arakunrin baba Saulu bá bi í pé, “Kí ni Samuẹli sọ fun yín?” Saulu dáhùn pé, “Ó sọ fún wa pé, dájúdájú, wọ́n ti rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.” Ṣugbọn Saulu kò sọ fún un pé, Samuẹli sọ fún òun pé òun yóo jọba. Samuẹli pe àwọn eniyan náà jọ siwaju OLUWA ní Misipa. Ó sọ fún wọn pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, ‘Mo kó yín jáde wá láti Ijipti, mo gbà yín kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti, ati gbogbo àwọn eniyan yòókù tí wọn ń ni yín lára.’ Ṣugbọn nisinsinyii ẹ ti kọ Ọlọrun yín sílẹ̀, Ọlọrun tí ó gbà yín kúrò lọ́wọ́ ìṣòro ati ìyọnu. Ẹ wí fún mi pé, ‘Yan ẹnìkan, tí yóo jọba lórí wa.’ Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan tò kọjá níwájú OLUWA ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́.” Nígbà náà ni, Samuẹli mú kí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan tò kọjá níwájú OLUWA, gègé sì mú ẹ̀yà Bẹnjamini. Lẹ́yìn náà Samuẹli mú kí àwọn ìdílé ìdílé tí ó wà ninu ẹ̀yà Bẹnjamini tò kọjá, gègé sì mú ìdílé Matiri. Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ọkunrin inú ìdílé Matiri bẹ̀rẹ̀ sí tò kọjá, gègé sì mú Saulu ọmọ Kiṣi. Ṣugbọn wọn kò rí i nígbà tí wọ́n wá a. Wọ́n bi OLUWA pé, “Àbí ọkunrin náà kò wá ni?” OLUWA dá wọn lóhùn pé, “Ó ti farapamọ́ sí ààrin àwọn ẹrù.” Wọ́n sáré lọ mú un jáde láti ibẹ̀. Nígbà tí ó dúró láàrin wọn, kò sí ẹni tí ó ga ju èjìká rẹ̀ lọ ninu wọn. Samuẹli bá wí fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹni tí OLUWA yàn nìyí. Kò sí ẹnikẹ́ni láàrin wa tí ó dàbí rẹ̀.” Gbogbo àwọn eniyan náà kígbe sókè pé, “Kí ọba kí ó pẹ́.” Samuẹli ṣe àlàyé àwọn ẹ̀tọ́ ati iṣẹ́ ọba fún àwọn eniyan náà. Ó kọ àwọn àlàyé náà sinu ìwé kan, ó sì gbé e siwaju OLUWA. Lẹ́yìn náà, ó ní kí olukuluku máa lọ sí ilé rẹ̀. Saulu náà bá pada lọ sí ilé rẹ̀ ní Gibea. Àwọn akọni ọkunrin bíi mélòó kan tí Ọlọrun ti fi sí ní ọkàn bá Saulu lọ. Ṣugbọn àwọn oníjàngbọ̀n kan dáhùn pé, “Báwo ni eléyìí ṣe lè gbà wá?” Wọ́n kẹ́gàn rẹ̀, wọn kò sì mú ẹ̀bùn wá fún un, ṣugbọn Saulu kò sọ̀rọ̀. Nahaṣi, ọba Amoni, kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n lọ gbógun ti ìlú Jabeṣi Gileadi. Àwọn ará Jabeṣi bá sọ fún Nahaṣi pé, “Jẹ́ kí á jọ dá majẹmu, a óo sì máa sìn ọ́.” Nahaṣi dá wọn lóhùn pé, “Ohun tí mo fi lè ba yín dá majẹmu ni pé, kí n yọ ojú ọ̀tún ẹnìkọ̀ọ̀kan yín, kí ó lè jẹ́ ìtìjú fún gbogbo Israẹli.” Àwọn àgbààgbà Jabeṣi dáhùn pé, “Fún wa ní ọjọ́ meje, kí á lè ranṣẹ jákèjádò ilẹ̀ Israẹli. Bí kò bá sí ẹni tí yóo gbà wá, a óo jọ̀wọ́ ara wa fún ọ.” Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ náà dé Gibea, níbi tí Saulu ń gbé, wọ́n ròyìn fún àwọn ará ìlú náà, gbogbo wọn sì pohùnréré ẹkún. Ní àkókò yìí gan-an ni Saulu ń ti oko rẹ̀ bọ̀, pẹlu àwọn akọ mààlúù rẹ̀. Ó bèèrè pé, “Kí ló ṣẹlẹ̀ tí gbogbo eniyan fi ń sọkún?” Wọ́n bá sọ ohun tí àwọn ará Jabeṣi sọ fún un. Nigba tí Saulu gbọ́ èyí, ẹ̀mí Ọlọrun bà lé Saulu inú sì bí i gidigidi. Ó mú akọ mààlúù meji, ó gé wọn sí wẹ́wẹ́, ó fi wọ́n ranṣẹ jákèjádò ilẹ̀ Israẹli, pẹlu ìkìlọ̀ pé, “Ẹnikẹ́ni tí kò bá tẹ̀lé Saulu ati Samuẹli lọ sójú ogun, bí a óo ti ṣe àwọn akọ mààlúù rẹ̀ nìyí.” Ìbẹ̀rù OLUWA mú àwọn ọmọ Israẹli, gbogbo wọn patapata jáde láì ku ẹnìkan. Saulu bá kó wọn jọ ní Beseki. Ọ̀kẹ́ mẹẹdogun (300,000) ni àwọn tí wọ́n wá láti ilẹ̀ Israẹli, àwọn tí wọ́n wá láti Juda sì jẹ́ ẹgbaa mẹẹdogun (30,000). Wọ́n sọ fún àwọn oníṣẹ́ tí wọ́n wá láti Jabeṣi-Gileadi pé, “Ẹ sọ fún àwọn eniyan yín pé, ní ọ̀sán ọ̀la, a óo gbà wọ́n kalẹ̀.” Nígbà tí àwọn ará Jabeṣi gbọ́ ìròyìn náà, inú wọn dùn gidigidi. Wọ́n wí fún Nahaṣi pé, “Lọ́la ni a óo jọ̀wọ́ ara wa fún ọ, ohunkohun tí ó bá sì wù ọ́ ni o lè fi wá ṣe.” Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, Saulu pín àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sí ọ̀nà mẹta, wọ́n kọlu ibùdó àwọn ọ̀tá wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n títí di ọ̀sán ọjọ́ náà. Àwọn tí kò kú lára wọn fọ́nká, tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi sí eniyan meji tí wọ́n dúró papọ̀. Àwọn ọmọ Israẹli bá bèèrè lọ́wọ́ Samuẹli pé, “Níbo ni àwọn tí wọ́n sọ pé kò yẹ kí Saulu jẹ ọba wa wà? Ẹ kó wọn jáde, kí á pa wọ́n.” Ṣugbọn Saulu dá wọn lóhùn pé, “A kò ní pa ẹnikẹ́ni lónìí, nítorí pé, òní ni ọjọ́ tí OLUWA gba Israẹli là.” Samuẹli wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí Giligali, kí á lè túbọ̀ fi ìdí ìjọba Saulu múlẹ̀.” Gbogbo wọn bá pada lọ sí Giligali, wọ́n sì fi Saulu jọba níwájú OLUWA. Wọ́n rú ẹbọ alaafia, Saulu ati àwọn ọmọ Israẹli sì jọ ṣe àjọyọ̀ ńlá. Lẹ́yìn náà, Samuẹli wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Mo ti ṣe ohun tí ẹ ní kí n ṣe. Mo ti fi ẹnìkan jọba lórí yín. Nisinsinyii, ọba ni yóo máa ṣe olórí yín. Ní tèmi, mo ti dàgbà, ogbó sì ti dé sí mi. Àwọn ọmọ mi sì ń bẹ lọ́dọ̀ yín. Láti ìgbà èwe mi ni mo ti jẹ́ olórí fun yín títí di àkókò yìí. Èmi nìyí níwájú yín yìí, bí mo bá ti ṣe nǹkankan tí kò tọ́, ẹ fi ẹ̀sùn kàn mí níwájú OLUWA ati ọba, ẹni àmì òróró rẹ̀. Ǹjẹ́ mo gba mààlúù ẹnikẹ́ni ninu yín rí? Àbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ta ni mo gbà rí? Ta ni mo rẹ́ jẹ rí? Tabi ta ni mo ni lára rí? Ǹjẹ́ mo gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni rí? Bí mo bá ti ṣe èyíkéyìí ninu àwọn nǹkan wọnyi rí, mo ṣetán láti san ohun tí mo gbà pada.” Àwọn eniyan náà dáhùn pé, “Rárá o, o kò rẹ́ wa jẹ rí, o kò ni wá lára, bẹ́ẹ̀ ni o kò sì gba ohunkohun lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni rí.” Samuẹli dáhùn pé, “OLUWA ati ọba, ẹni àmì òróró rẹ̀ ni ẹlẹ́rìí lónìí pé, ẹ gbà pé ọwọ́ mi mọ́ patapata.” Àwọn eniyan náà dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, OLUWA ni ẹlẹri wa.” Samuẹli tún sọ fún wọn pé, “OLUWA tí ó yan Mose ati Aaroni, tí ó kó àwọn baba ńlá yín jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti ni ẹlẹ́rìí. Ẹ dúró jẹ́ẹ́, n óo sì fi ẹ̀sùn kàn yín níwájú OLUWA n óo ran yín létí gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá tí OLUWA ṣe láti gba àwọn baba ńlá yín kalẹ̀. Nígbà tí Jakọbu ati ìdílé rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Ijipti, tí àwọn ará Ijipti ń ni wọ́n lára, àwọn baba ńlá yín kígbe pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́, OLUWA sì rán Mose ati Aaroni, wọ́n kó wọn jáde kúrò ní Ijipti. Ó sì mú kí wọ́n máa gbé orí ilẹ̀ yìí. Ṣugbọn wọ́n gbàgbé OLUWA Ọlọrun wọn. Wọ́n jagun, OLUWA sì fi wọ́n lé Sisera, olórí ogun Jabini ọba Hasori lọ́wọ́, àwọn ará Filistia ati ọba Moabu náà sì ṣẹgun wọn. Lẹ́yìn náà, àwọn baba ńlá yín kígbe pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́. Wọ́n ní, ‘A ti ṣẹ̀, nítorí pé a ti kọ OLUWA sílẹ̀, a sì ń sin oriṣa Baali, ati ti Aṣitarotu. Nisinsinyii, gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, a óo sì máa sìn ọ́.’ OLUWA bá rán Jerubaali ati Baraki, ati Jẹfuta ati èmi, Samuẹli, láti gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín káàkiri, ó sì jẹ́ kí ẹ wà ní alaafia. Ṣugbọn nígbà tí ẹ rí i pé Nahaṣi, ọba Amoni fẹ́ gbé ogun tì yín, ẹ kọ OLUWA lọ́ba, ẹ wí fún mi pé, ẹ fẹ́ ọba tí yóo jẹ́ alákòóso yín. “Ọba tí ẹ bèèrè fún náà nìyí, ẹ̀yin ni ẹ bèèrè rẹ̀, OLUWA sì ti fun yín nisinsinyii. Bí ẹ bá bẹ̀rù OLUWA, tí ẹ̀ ń sìn ín, tí ẹ̀ ń gbọ́ tirẹ̀, tí ẹ sì ń pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, tí ẹ̀yin ati ọba tí ń ṣe àkóso yín bá ń tẹ̀lé àwọn ìlànà OLUWA Ọlọrun yín, ohun gbogbo ni yóo máa lọ déédé fun yín. Ṣugbọn bí ẹ kò bá gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ kò sì pa òfin rẹ̀ mọ́, yóo dojú ìjà kọ ẹ̀yin ati ọba yín. Nítorí náà, ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ wo iṣẹ́ ńlá tí OLUWA yóo ṣe. Àkókò ìkórè ọkà nìyí, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? N óo gbadura, OLUWA yóo sì jẹ́ kí ààrá sán, kí òjò sì rọ̀. Nígbà tí èyí bá ṣẹlẹ̀, ẹ óo mọ̀ pé bíbèèrè tí ẹ bèèrè fún ọba, ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni ẹ dá sí OLUWA.” Samuẹli bá gbadura, ní ọjọ́ náà gan-an, OLUWA sán ààrá, ó sì rọ òjò. Ẹ̀rù OLUWA ati ti Samuẹli sì ba gbogbo àwọn eniyan náà. Wọ́n bá wí fún Samuẹli pé, “Gbadura sí OLUWA Ọlọrun rẹ fún wa, kí á má baà kú. Nítorí pé a mọ̀ nisinsinyii pé, yàtọ̀ fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí a ti dá tẹ́lẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀ tún ni bíbèèrè tí a bèèrè fún ọba tún jẹ́ lọ́rùn wa.” Samuẹli dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má bẹ̀rù, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí ẹ ṣe burú, sibẹsibẹ ẹ má ṣe yipada kúrò lọ́dọ̀ OLUWA, ṣugbọn ẹ máa sìn ín pẹlu gbogbo ọkàn yín. Ẹ má tẹ̀lé àwọn oriṣa; ohun asán tí kò lérè, tí kò sì lè gbani ni wọ́n. OLUWA kò ní ta eniyan rẹ̀ nù, nítorí orúkọ ńlá rẹ̀, nítorí pé ó wù ú láti ṣe yín ní eniyan rẹ̀. Ní tèmi, n kò ní ṣẹ̀, nípa aigbadura sí OLUWA fun yín. N óo sì máa kọ yín ní ohun tí ó dára láti máa ṣe ati ọ̀nà tí ó tọ́ fun yín láti máa rìn. Ẹ máa bẹ̀rù OLUWA, kí ẹ sì máa sìn ín pẹlu gbogbo ọkàn yín. Ẹ ranti àwọn nǹkan ńláńlá tí ó ti ṣe fun yín. Ṣugbọn bí ẹ bá tún ṣe nǹkan burúkú, yóo pa ẹ̀yin ati ọba yín run.” Saulu jẹ́ bíi ọmọ ọgbọ̀n ọdún... nígbà tí ó jọba lórí Israẹli. Ó sì wà lórí oyè fún bíi ogoji ọdún. Saulu yan ẹgbẹẹdogun (3,000) ọkunrin. Ó fi ẹgbaa (2,000) ninu wọn sọ́dọ̀ ara rẹ̀ ní Mikimaṣi, ní agbègbè olókè ti Bẹtẹli. Ẹgbẹrun (1,000) yòókù wà lọ́dọ̀ Jonatani, ọmọ rẹ̀, ní Gibea, ní agbègbè ẹ̀yà Bẹnjamini. Ó bá dá àwọn yòókù pada sí ilé wọn. Jonatani ṣẹgun ọ̀wọ́ ọmọ ogun Filistini tí wọ́n wà ní Geba; gbogbo àwọn ará Filistia sì gbọ́ nípa rẹ̀. Saulu bá fọn fèrè ogun jákèjádò ilẹ̀ náà, wí pé “Ẹ jẹ́ kí àwọn Heberu gbọ́ èyí.” Gbogbo Israẹli gbọ́ pé Saulu ti ṣẹgun ọ̀wọ́ ọmọ ogun Filistini ati pé àwọn ọmọ Israẹli ti di ohun ìríra lójú àwọn ará Filistia. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá jáde láti wá darapọ̀ mọ́ Saulu ní Giligali. Àwọn ará Filistia kó ara wọn jọ láti bá Israẹli jagun. Wọ́n ní ẹgbaa mẹẹdogun (30,000) kẹ̀kẹ́ ogun, ati ẹgbaata (6,000) ẹlẹ́ṣin, àwọn ọmọ ogun wọn sì pọ̀ bí eṣú. Wọ́n lọ sí Mikimaṣi ní ìhà ìlà oòrùn Betafeni, wọ́n pàgọ́ wọn sibẹ. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli rí i pé ilẹ̀ ti ká àwọn mọ́, nítorí ọwọ́ àwọn ọmọ ogun Filistini dùn wọ́n, wọ́n bá ń farapamọ́ káàkiri; àwọn kan sá sinu ihò ilẹ̀, àwọn mìíràn sì sá sinu àpáta, inú ibojì ati inú kànga. Àwọn mìíràn ninu wọn ré odò Jọdani kọjá sí agbègbè Gadi ati Gileadi. Gbogbo àwọn tí wọ́n wà pẹlu Saulu sì wà ninu ìbẹ̀rù ńlá. Ọjọ́ meje ni ó fi dúró de Samuẹli, bí Samuẹli ti wí. Ṣugbọn Samuẹli kò wá sí Giligali. Àwọn eniyan bá bẹ̀rẹ̀ sí sá kúrò lẹ́yìn Saulu. Nítorí náà, Saulu ní kí wọ́n gbé ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia wá fún òun, ó sì rú ẹbọ. Bí ó ti parí rírú ẹbọ sísun náà tán ni Samuẹli dé. Saulu lọ pàdé rẹ̀, ó sì kí i káàbọ̀. Ṣugbọn Samuẹli wí fún un pé, “Kí lo dánwò yìí?” Saulu bá dá a lóhùn pé, “Àwọn eniyan náà ti bẹ̀rẹ̀ sí sá kúrò lẹ́yìn mi, o kò sì dé ní àkókò tí o dá. Àwọn ará Filistia sì ti kó ara wọn jọ ní Mikimaṣi. Mo wá rò ó wí pé, àwọn ará Filistia tí ń bọ̀ wá gbógun tì mí ní Giligali níhìn-ín, n kò sì tíì wá ojurere OLUWA. Ni mo bá rú ẹbọ sísun.” Samuẹli bá wí fún un pé, “Ìwà òmùgọ̀ patapata gbáà ni èyí. O kò pa òfin tí OLUWA Ọlọrun rẹ fún ọ mọ́. Bí ó bá jẹ́ pé o gbọ́ tirẹ̀ ni, nisinsinyii ni OLUWA ìbá fìdí ìjọba rẹ múlẹ̀ lórí Israẹli títí lae. Ṣugbọn nisinsinyii, ìjọba rẹ kò ní jẹ́ títí lae, nítorí pé, o ti ṣe àìgbọràn sí OLUWA. Ó ti wá ẹni tí ó fẹ́, ó sì ti yàn án láti jẹ́ olórí fún àwọn eniyan rẹ̀, nítorí pé, o kò pa òfin OLUWA rẹ mọ́.” Samuẹli kúrò ní Giligali, ó lọ sí Gibea ní Bẹnjamini. Saulu ka àwọn eniyan tí wọ́n kù lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n jẹ́ ẹgbẹta (600). Saulu ati Jonatani, ọmọ rẹ̀, pẹlu àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ pàgọ́ sí Geba ní agbègbè Bẹnjamini. Àgọ́ ti àwọn ará Filistia wà ní Mikimaṣi. Àwọn ẹgbẹ́ ọlọ́ṣà, mẹta ninu ọmọ ogun Filistini jáde láti inú àgọ́ wọn, àwọn kan lọ sí apá ọ̀nà Ofira ní agbègbè Ṣuali, àwọn kan lọ sí apá ọ̀nà Beti Horoni, àwọn yòókù lọ sí ẹ̀bá ìpínlẹ̀ àtiwọ àfonífojì Seboimu ní ọ̀nà aṣálẹ̀. Kò sí ẹyọ alágbẹ̀dẹ kan ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli, nítorí pé àwọn ará Filistia ti pinnu pé, àwọn kò ní gba àwọn ọmọ Israẹli láyè láti rọ idà ati ọ̀kọ̀ fúnra wọn. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli bá fẹ́ pọ́n ohun ìtúlẹ̀ wọn ati ọkọ́ ati àáké ati dòjé, wọ́n níláti lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Filistia. Owó díẹ̀ ni àwọn Filistia máa ń gbà, láti bá wọn pọ́n ohun ìtúlẹ̀ ati ọkọ́, wọ́n ń gba ìdámẹ́ta owó ṣekeli láti pọ́n àáké ati láti tún irin tí ó wà lára ohun ìtúlẹ̀ ṣe. Nítorí náà, ní ọjọ́ ogun yìí kò sí ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli tí ó ní idà tabi ọ̀kọ̀ lọ́wọ́, àfi Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀. Ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun Filistini kan sì lọ sí ọ̀nà Mikimaṣi. Ní ọjọ́ kan, Jonatani, ọmọ Saulu, wí fún ọdọmọkunrin tí ó ń ru ihamọra rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí á lọ sí òdìkejì ibùdó àwọn ọmọ ogun Filistini.” Ṣugbọn Jonatani kò sọ fún Saulu, baba rẹ̀. Ní àkókò yìí, baba rẹ̀ pàgọ́ ogun rẹ̀ sí abẹ́ igi pomegiranate kan ní Migironi, nítòsí Gibea. Àwọn ọmọ ogun bíi ẹgbẹta (600) wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ẹni tí ó jẹ́ alufaa tí ó ń wọ ẹ̀wù efodu nígbà náà ni Ahija, ọmọ Ahitubu, arakunrin Ikabodu, ọmọ Finehasi, ọmọ Eli, tíí ṣe alufaa OLUWA ní Ṣilo. Àwọn ọmọ ogun kò mọ̀ pé Jonatani ti kúrò lọ́dọ̀ àwọn. Àwọn òkúta ńláńlá meji kan wà ní ọ̀nà kan, tí ó wà ní àfonífojì Mikimaṣi. Pàlàpálá òkúta wọnyi ni Jonatani gbà lọ sí ibùdó ogun àwọn Filistini. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn òkúta náà wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji ọ̀nà náà. Orúkọ ekinni ń jẹ́ Bosesi, ekeji sì ń jẹ́ Sene. Èyí ekinni wà ní apá àríwá ọ̀nà náà, ó dojú kọ Mikimaṣi. Ekeji sì wà ní apá gúsù, ó dojú kọ Geba. Jonatani bá pe ọdọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀, ó ní, “Jẹ́ kí á rékọjá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Filistia, àwọn aláìkọlà wọnyi, bóyá OLUWA a jẹ́ ràn wá lọ́wọ́. Bí OLUWA bá fẹ́ ran eniyan lọ́wọ́, kò sí ohun tí ó lè dí i lọ́wọ́, kì báà jẹ́ pé eniyan pọ̀ ni, tabi wọn kò pọ̀.” Ọdọmọkunrin náà dá a lóhùn pé, “Ohunkohun tí ọkàn rẹ bá fẹ́ ni kí o ṣe. Mo wà lẹ́yìn rẹ, bí ọkàn rẹ ti rí ni tèmi náà rí.” Jonatani bá dáhùn pé, “Ó dára, a óo rékọjá sọ́hùn-ún, a óo sì fi ara wa han àwọn ará Filistia. Bí wọ́n bá ní kí á dúró kí àwọn tọ̀ wá wá, a óo dúró níbi tí a bá wà, a kò ní lọ sọ́dọ̀ wọn. Ṣugbọn bí wọ́n bá ní kí á máa bọ̀ lọ́dọ̀ àwọn, a óo tọ̀ wọ́n lọ. Èyí ni yóo jẹ́ àmì fún wa, pé OLUWA ti fún wa ní ìṣẹ́gun lórí wọn.” Nítorí náà, wọ́n fi ara wọn han àwọn ará Filistia. Bí àwọn ara Filistia ti rí wọn, wọ́n ní, “Ẹ wò ó! Àwọn Heberu ń jáde bọ̀ wá láti inú ihò òkúta tí wọ́n farapamọ́ sí.” Wọ́n bá nahùn pe Jonatani ati ọdọmọkunrin tí ó ń ru ihamọra rẹ̀; wọ́n ní, “Ẹ máa gòkè tọ̀ wá bọ̀ níhìn-ín, a óo fi nǹkankan hàn yín.” Jonatani bá wí fún ọdọmọkunrin náà pé, “Tẹ̀lé mi, OLUWA ti fún Israẹli ní ìṣẹ́gun lórí wọn.” Jonatani bá rápálá gun òkè náà, ọdọmọkunrin tí ó ń ru ihamọra rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Jonatani bá bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ará Filistia jà, wọ́n sì ń ṣubú níwájú rẹ̀, bí wọ́n ti ń ṣubú ni ọdọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀ ń pa wọ́n. Ní àkókò tí wọ́n kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n, Jonatani ati ọdọmọkunrin yìí pa nǹkan bí ogún eniyan. Ààrin ibi tí wọ́n ti ja ìjà yìí kò ju nǹkan bí ìdajì sarè oko kan lọ. Ẹ̀rù ba gbogbo àwọn ará Filistia tí wọ́n wà ní ibùdó, ati àwọn tí wọ́n wà ninu pápá, ati gbogbo eniyan. Àwọn ọmọ ogun Filistini ati àwọn ẹgbẹ́ ogun tí wọ́n ń digun-jalè wárìrì, ilẹ̀ mì tìtì, jìnnìjìnnì sì dà bo gbogbo wọn. Àwọn ọmọ ogun Saulu tí wọn ń ṣọ́nà ní Gibea, ní agbègbè Bẹnjamini, rí i tí àwọn ọmọ ogun Filistini ń sá káàkiri. Saulu bá pàṣẹ fún àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé kí wọ́n ka gbogbo àwọn ọmọ ogun, láti mọ àwọn tí wọ́n jáde kúrò láàrin wọn. Wọ́n bá ka àwọn ọmọ ogun, wọ́n sì rí i pé Jonatani ati ọdọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀ kò sí láàrin wọn. Saulu wí fún Ahija, alufaa pé, “Gbé àpótí Ọlọrun wá níhìn-ín.” Nítorí àpótí Ọlọrun ń bá àwọn ọmọ ogun Israẹli lọ ní àkókò náà. Bí Saulu ti ń bá alufaa náà sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ìdàrúdàpọ̀ tí ó wà ninu àgọ́ àwọn ọmọ ogun Filistini ń pọ̀ sí i. Nítorí náà, Saulu wí fún un pé kí ó dáwọ́ dúró. Saulu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kó ara wọn jọ, wọ́n lọ sójú ogun náà. Wọ́n bá àwọn ọmọ ogun ninu ìdàrúdàpọ̀ níbi tí wọ́n ti ń pa ara wọn. Àwọn Heberu tí wọ́n ti wà lẹ́yìn àwọn ará Filistia tẹ́lẹ̀, tí wọ́n sì bá wọn lọ sí ibùdó ogun wọn, yipada kúrò lẹ́yìn wọn, wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun Israẹli tí wọ́n wà pẹlu Saulu ati Jonatani. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ti farapamọ́ káàkiri agbègbè olókè Efuraimu gbọ́ pé àwọn ará Filistia ti bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ; wọ́n yára dara pọ̀ mọ́ Saulu, wọ́n dojú ìjà kọ àwọn ọmọ ogun Filistini. Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe ṣẹgun fún àwọn ọmọ Israẹli ní ọjọ́ náà, wọ́n sì ja ogun náà kọjá Betafeni. Ara àwọn ọmọ ogun Israẹli ti hù ní ọjọ́ náà, àárẹ̀ sì mú wọn, nítorí pé Saulu ti fi ìbúra pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ẹnu kan nǹkankan títí di àṣáálẹ́ ọjọ́ náà, títí tí òun yóo fi gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá òun, olúwarẹ̀ gbé! Nítorí náà, kò sí ẹnikẹ́ni ninu wọn tí ó fi ẹnu kan nǹkankan. Gbogbo wọn dé inú igbó, wọ́n rí oyin nílẹ̀. Nígbà tí wọ́n wọ inú igbó náà, wọ́n rí i tí oyin ń kán sílẹ̀, ṣugbọn kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè fi ọwọ́ kàn án nítorí pé wọ́n bẹ̀rù ìbúra Saulu. Ṣugbọn Jonatani kò gbọ́ nígbà tí baba rẹ̀ ń fi ìbúra pàṣẹ fún àwọn eniyan náà. Nítorí náà, ó na ọ̀pá tí ó mú lọ́wọ́, ó tì í bọ inú afárá oyin kan, ó sì lá a. Lẹsẹkẹsẹ ojú rẹ̀ wálẹ̀. Ọ̀kan ninu àwọn eniyan náà wí fún un pé, “Ebi ń pa gbogbo wa kú lọ, ṣugbọn baba rẹ ti búra pé, ‘Ègbé ni fún ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ẹnu kan nǹkankan lónìí.’ ” Jonatani dáhùn pé, “Ohun tí baba mi ṣe sí àwọn eniyan wọnyi kò dára, wò ó bí ojú mi ti wálẹ̀ nígbà tí mo lá oyin díẹ̀. Báwo ni ìbá ti dára tó lónìí, bí ó bá jẹ́ pé àwọn eniyan jẹ lára ìkógun àwọn ọ̀tá wọn tí wọ́n rí. Àwọn ará Filistia tí wọn ìbá pa ìbá ti pọ̀ ju èyí lọ.” Wọ́n pa àwọn ọmọ ogun Filistini ní ọjọ́ náà, láti Mikimaṣi títí dé Aijaloni; ó sì rẹ àwọn eniyan náà gidigidi. Nítorí náà, wọ́n sáré sí ìkógun, wọ́n pa àwọn aguntan ati mààlúù ati ọmọ mààlúù, wọ́n sì ń jẹ wọ́n tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀. Wọ́n bá lọ sọ fún Saulu pé, “Àwọn eniyan ń dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA nítorí wọ́n ń jẹ ẹran tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀.” Saulu bá wí pé, “Ìwà ọ̀dàlẹ̀ ni ẹ hù yìí. Ẹ yí òkúta ńlá kan wá sọ́dọ̀ mi níhìn-ín.” Ó tún pàṣẹ pé, “Ẹ lọ sí ààrin àwọn eniyan, kí ẹ sì wí fún wọn pé, kí wọ́n kó mààlúù wọn ati aguntan wọn wá síhìn-ín. Níhìn-ín ni kí wọ́n ti pa wọ́n, kí wọ́n sì jẹ wọ́n. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ ẹran tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀, kí wọ́n dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA.” Nítorí náà, gbogbo wọn kó mààlúù wọn lọ sí ọ̀dọ̀ Saulu ní alẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n sì pa wọ́n níbẹ̀. Saulu bá tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA. Pẹpẹ yìí ni pẹpẹ kinni tí Saulu tẹ́ fún OLUWA. Saulu wí fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ kọlu àwọn ará Filistia ní òru kí á kó ẹrù wọn, kí á sì pa gbogbo wọn títí ilẹ̀ yóo fi mọ́ láì dá ẹnikẹ́ni sí.” Àwọn eniyan náà dá a lóhùn pé, “Ṣe èyí tí ó bá dára lójú rẹ.” Ṣugbọn alufaa wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á kọ́kọ́ bèèrè lọ́wọ́ Ọlọrun ná.” Saulu bá bèèrè lọ́wọ́ Ọlọrun pé, “Ṣé kí n lọ kọlu àwọn ará Filistia? Ṣé o óo fún Israẹli ní ìṣẹ́gun?” Ṣugbọn Ọlọrun kò dá a lóhùn ní ọjọ́ náà. Saulu bá pe gbogbo olórí àwọn eniyan náà jọ, ó ní, “Ẹ jẹ́ kí á wádìí ohun tí ó fa ẹ̀ṣẹ̀ òní. Mo fi OLUWA alààyè tí ó fún Israẹli ní ìṣẹ́gun búra pé, pípa ni a óo pa ẹni tí ó bá jẹ̀bi ọ̀rọ̀ yìí, kì báà jẹ́ Jonatani ọmọ mi.” Ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò dá a lóhùn ninu wọn. Saulu bá wí fún gbogbo Israẹli pé, “Gbogbo yín, ẹ dúró ní apá kan, èmi ati Jonatani, ọmọ mi, yóo dúró ní apá keji.” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ṣe ohun tí ó bá tọ́ lójú rẹ.” Saulu bá ní, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, kí ló dé tí o kò fi dá iranṣẹ rẹ lóhùn lónìí? OLUWA Ọlọrun Israẹli, bí ó bá jẹ́ pé èmi tabi Jonatani ni a jẹ̀bi, fi Urimu dáhùn. Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé àwọn eniyan rẹ ni wọ́n ṣẹ̀, fi Tumimu dáhùn.” Urimu bá mú Jonatani ati Saulu, Saulu ní, “Ẹ ṣẹ́ gègé láàrin èmi ati Jonatani, ọmọ mi.” Gègé bá mú Jonatani. Saulu bèèrè lọ́wọ́ Jonatani pé kí ó sọ ohun tí ó ṣe fún òun. Jonatani dá a lóhùn pé, “Mo ti ọ̀pá tí mo mú lọ́wọ́ bọ inú oyin, mo sì lá a. Èmi nìyí, mo ṣetán láti kú.” Saulu dá a lóhùn pé, “Láì sí àní àní, pípa ni wọn yóo pa ọ́; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí Ọlọrun lù mí pa.” Nígbà náà ni àwọn eniyan wí fún Saulu pé, “Ṣé a óo pa Jonatani ni, ẹni tí ó ti ṣẹ́ ogun ńlá fún Israẹli? Kí á má rí i. Bí OLUWA tí ń bẹ láàyè, ẹyọ irun orí rẹ̀ kan kò ní bọ́ sílẹ̀. Agbára Ọlọrun ni ó fi ṣe ohun tí ó ṣe lónìí.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan náà ṣe gba Jonatani kalẹ̀, tí wọn kò sì jẹ́ kí wọ́n pa á. Lẹ́yìn èyí, Saulu kò lépa àwọn ará Filistia mọ́. Àwọn Filistini sì pada lọ sí agbègbè wọn. Lẹ́yìn tí Saulu ti di ọba Israẹli tán, ó bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ọ̀tá tí wọ́n yí i ká jagun; àwọn bíi: Moabu, Amoni, ati Edomu, ọba ilẹ̀ Soba, ati ti ilẹ̀ Filistini. Ní gbogbo ibi tí ó ti jagun ni ó ti pa wọ́n ní ìpakúpa. Ó jagun gẹ́gẹ́ bí akikanju, ó ṣẹgun àwọn ará Amaleki. Ó sì gba Israẹli kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tí wọn ń fi ogun kó wọn. Àwọn ọmọ Saulu lọkunrin ni Jonatani, Iṣifi, ati Malikiṣua. Orúkọ ọmọbinrin rẹ̀ àgbà ni Merabu, ti èyí àbúrò ni Mikali. Ahinoamu ọmọ Ahimaasi ni aya Saulu. Abineri ọmọ Neri, arakunrin baba Saulu, sì ni balogun rẹ̀. Kiṣi ni baba Saulu. Neri, baba Abineri jẹ́ ọmọ Abieli. Gbogbo ọjọ́ ayé Saulu ni ó fi bá àwọn ará Filistia jagun kíkankíkan. Nígbà gbogbo tí Saulu bá sì ti rí ọkunrin tí ó jẹ́ alágbára tabi akikanju, a máa fi kún àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Samuẹli sọ fún Saulu pé, “OLUWA rán mi láti fi òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli, eniyan rẹ̀. Nisinsinyii gbọ́ ohun tí OLUWA wí. OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, ‘N óo jẹ àwọn ará Amaleki níyà nítorí pé wọ́n gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli, nígbà tí wọ́n ń bọ̀ láti Ijipti. Lọ gbógun ti àwọn ará Amaleki, kí o sì run gbogbo nǹkan tí wọ́n ní patapata. O kò gbọdọ̀ dá nǹkankan sí, pa gbogbo wọn, atọkunrin, atobinrin; àtàwọn ọmọ kéékèèké; àtàwọn ọmọ ọmú; ati mààlúù, ataguntan, ati ràkúnmí ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, gbogbo wọn pátá ni kí o pa.’ ” Saulu bá kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ, ó ka iye wọn ní Telaimu. Àwọn tí wọ́n wá láti ilẹ̀ Israẹli jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000). Àwọn tí wọ́n wá láti ilẹ̀ Juda sì jẹ́ ẹgbaarun (10,000). Òun ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ bá lọ sí ìlú Amaleki, wọ́n ba ní ibùba, ní àfonífojì. Saulu ranṣẹ ìkìlọ̀ kan sí àwọn ará Keni pé, “Ẹ jáde kúrò láàrin àwọn ará Amaleki, kí n má baà pa yín run, nítorí pé ẹ̀yin ṣàánú àwọn ọmọ Israẹli nígbà tí wọn ń bọ̀ láti Ijipti.” Àwọn ará Keni bá jáde kúrò láàrin àwọn ará Amaleki. Saulu ṣẹgun àwọn ará Amaleki láti Hafila títí dé Ṣuri ní ìhà ìlà oòrùn Ijipti. Ó mú Agagi, ọba àwọn ará Amaleki láàyè, ó sì fi idà pa gbogbo àwọn eniyan rẹ̀. Ṣugbọn Saulu ati àwọn eniyan rẹ̀ dá Agagi sí, wọn kò sì pa àwọn tí wọ́n dára jùlọ ninu àwọn aguntan, mààlúù, ati ọ̀dọ́ mààlúù ati ọ̀dọ́ aguntan wọn, ati àwọn nǹkan mìíràn tí ó dára. Wọn kò pa wọ́n run, ṣugbọn wọ́n pa àwọn ohun tí kò níláárí run. OLUWA sọ fún Samuẹli pé, “Ó dùn mí pé mo fi Saulu jọba. Ó ti yipada kúrò lẹ́yìn mi, kò sì pa òfin mi mọ́.” Inú bí Samuẹli, ó sì gbadura sí OLUWA ní gbogbo òru ọjọ́ náà. Ní kutukutu òwúrọ̀ ọjọ́ keji, ó jáde, ó lọ rí Saulu. Ó gbọ́ pé Saulu ti lọ sí Kamẹli, níbi tí ó ti gbé ọ̀wọ̀n kan kalẹ̀, ní ìrántí ara rẹ̀, ati pé ó ti gba ibẹ̀ lọ sí Giligali. Samuẹli bá lọ sọ́dọ̀ Saulu. Saulu sọ fún un pé, “Kí OLUWA kí ó bukun ọ, Samuẹli, mo ti pa òfin OLUWA mọ́.” Samuẹli bá bi í pé, “Èwo ni igbe àwọn aguntan ati ti àwọn mààlúù tí mò ń gbọ́ yìí?” Saulu dá a lóhùn pé, “Àwọn eniyan mi ni wọ́n kó wọn lọ́dọ̀ àwọn ará Amaleki. Wọ́n ṣa àwọn aguntan ati àwọn mààlúù tí wọ́n dára jùlọ pamọ́ láti fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun rẹ. A sì ti pa gbogbo àwọn yòókù run patapata.” Samuẹli bá sọ fún un pé, “Dákẹ́! Jẹ́ kí n sọ ohun tí OLUWA wí fún mi ní alẹ́ àná fún ọ.” Saulu dáhùn pé, “Mò ń gbọ́.” Samuẹli ní, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o kò jámọ́ nǹkankan lójú ara rẹ, sibẹsibẹ ìwọ ni olórí gbogbo ẹ̀yà Israẹli. Ìwọ ni OLUWA fi òróró yàn ní ọba wọn. Ó sì rán ọ jáde pẹlu àṣẹ pé kí o pa gbogbo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ará Amaleki run. Ó ní kí o gbógun tì wọ́n títí o óo fi pa wọ́n run patapata. Kí ló dé tí o kò fi pa àṣẹ OLUWA mọ? Kí ló dé tí o fi kó ìkógun, tí o sì ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA?” Saulu dá a lóhùn pé, “Mo ti pa òfin OLUWA mọ́, mo jáde lọ bí o ti wí fún mi pé kí n jáde lọ, mo mú Agagi ọba pada bọ̀, mo sì pa gbogbo àwọn ará Amaleki run. Ṣugbọn àwọn eniyan mi ni wọ́n kó ìkógun aguntan ati àwọn mààlúù tí ó dára jùlọ lára àwọn ohun tí a ti yà sọ́tọ̀ fún ìparun láti fi wọ́n rúbọ sí OLUWA Ọlọrun rẹ ní Giligali.” Samuẹli bá bi í pé, “Èwo ló dùn mọ́ OLUWA jù, ìgbọràn ni, tabi ọrẹ ati ẹbọ sísun?” Ó ní, “Gbọ́! Ìgbọràn dára ju ẹbọ lọ, ìfetísílẹ̀ sì dára ju ọ̀rá àgbò lọ. Ẹni tí ń ṣe oríkunkun sí OLUWA ati ẹni tí ó ṣẹ́ṣó, bákan náà ni wọ́n rí; ẹ̀ṣẹ̀ ìgbéraga ati ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà kò sì yàtọ̀. Nítorí pé, o kọ òfin OLUWA, OLUWA ti kọ ìwọ náà ní ọba.” Saulu wí fún Samuẹli pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo ti dẹ́ṣẹ̀. Mo ti ṣe àìgbọràn sí òfin OLUWA ati sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nítorí pé mo bẹ̀rù àwọn eniyan mi, mo sì ṣe ohun tí wọ́n fẹ́. Nítorí náà, mo bẹ̀ ọ́, dáríjì mí, kí o sì bá mi pada, kí n lọ sin OLUWA níbẹ̀.” Samuẹli dá a lóhùn pé, “N kò ní bá ọ pada lọ. O ti kọ òfin OLUWA sílẹ̀, OLUWA sì ti kọ ìwọ náà ní ọba Israẹli.” Samuẹli bá yipada, ó fẹ́ máa lọ. Ṣugbọn Saulu fa ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀, ó sì ya. Samuẹli bá wí fún un pé, “OLUWA ti fa ìjọba Israẹli ya mọ́ ọ lọ́wọ́ lónìí, ó sì ti fi fún aládùúgbò rẹ tí ó sàn jù ọ́ lọ. Ọlọrun Ológo Israẹli kò jẹ́ parọ́, kò sì jẹ́ yí ọkàn rẹ̀ pada; nítorí pé kì í ṣe eniyan, tí ó lè yí ọkàn pada.” Saulu dá a lóhùn pé, “Mo mọ̀ pé mo ti ṣẹ̀, ṣugbọn bu ọlá fún mi níwájú àwọn àgbààgbà, àwọn eniyan mi ati gbogbo Israẹli. Bá mi pada lọ, kí n lọ sin OLUWA Ọlọrun rẹ.” Samuẹli bá bá a pada, Saulu sì sin OLUWA níbẹ̀. Samuẹli pàṣẹ pé kí wọ́n mú Agagi, ọba Amaleki wá, Agagi bá jáde tọ̀ ọ́ lọ pẹlu ìbàlẹ̀ ọkàn, ó ní, “Dájúdájú oró ikú ti rékọjá lórí mi.” Samuẹli bá sọ fún un pé, “Bí idà rẹ ti sọ ọpọlọpọ ìyá di aláìlọ́mọ, bẹ́ẹ̀ ni ìyá tìrẹ náà yóo di aláìlọ́mọ láàrin àwọn obinrin.” Samuẹli bá gé Agagi wẹ́lẹwẹ̀lẹ níwájú pẹpẹ ní Giligali. Lẹ́yìn náà, Samuẹli pada lọ sí Rama, Saulu ọba sì pada lọ sí ilé rẹ̀ ní Gibea ti Saulu. Samuẹli kò tún fi ojú kan Saulu mọ títí tí Samuẹli fi kú, ṣugbọn inú Samuẹli bàjẹ́ nítorí rẹ̀. Ọkàn OLUWA sì bàjẹ́ pé òun fi Saulu jọba Israẹli. OLUWA wí fún Samuẹli pé, “Ìgbà wo ni o fẹ́ káàánú lórí Saulu dà? Ṣebí o mọ̀ pé mo ti kọ̀ ọ́ lọ́ba lórí Israẹli. Rọ òróró kún inú ìwo rẹ kí o lọ sọ́dọ̀ Jese ará Bẹtilẹhẹmu, mo ti yan ọba kan fún ara mi ninu àwọn ọmọ rẹ̀.” Samuẹli dáhùn pé, “Báwo ni n óo ṣe lọ? Bí Saulu bá gbọ́, pípa ni yóo pa mí.” OLUWA dá a lóhùn pé, “Mú ọ̀dọ́ mààlúù kan lọ́wọ́, kí o wí pé o wá rúbọ sí OLUWA ni. Pe Jese wá sí ibi ẹbọ náà, n óo sì sọ ohun tí o óo ṣe fún ọ. N óo dárúkọ ẹnìkan fún ọ, ẹni náà ni kí o fi jọba.” Samuẹli ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ fún un, ó lọ sí Bẹtilẹhẹmu. Gbígbọ̀n ni àwọn àgbààgbà ìlú bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n bí wọ́n ti ń lọ pàdé rẹ̀. Wọ́n bi í pé, “Ṣé alaafia ni?” Samuẹli dáhùn pé, “Alaafia ni. Ẹbọ ni mo wá rú sí OLUWA. Ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ bá mi lọ síbi ìrúbọ náà.” Ó ya Jese ati àwọn ọmọ rẹ̀ sí mímọ́, ó sì pè wọ́n síbi ìrúbọ náà. Nígbà tí wọ́n dé, ó wo Eliabu, ó sì wí ninu ara rẹ̀ pé, “Dájúdájú ẹni tí OLUWA yàn nìyí.” Ṣugbọn OLUWA wí fún Samuẹli pé, “Má ṣe wo ìrísí rẹ̀ tabi gíga rẹ̀, nítorí pé, mo ti kọ̀ ọ́. OLUWA kìí wo nǹkan bí eniyan ti ń wò ó, eniyan a máa wo ojú, ṣugbọn OLUWA a máa wo ọkàn.” Lẹ́yìn náà, Jese sọ fún Abinadabu pé kí ó kọjá níwájú Samuẹli. Samuẹli wí pé, “OLUWA kò yan eléyìí.” Lẹ́yìn náà Jese sọ fún Ṣama pé kí ó kọjá níwájú Samuẹli. Samuẹli tún ní, “OLUWA kò yan eléyìí náà.” Jese mú kí àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeje kọjá níwájú Samuẹli. Ṣugbọn Samuẹli wí fún un pé, OLUWA kò yan ọ̀kankan ninu wọn. Samuẹli bá bèèrè lọ́wọ́ Jese pé, “Ṣé gbogbo àwọn ọmọ rẹ ọkunrin nìyí?” Jese dáhùn, ó ní, “Ó ku èyí tí ó kéré jù, ṣugbọn ó ń tọ́jú agbo ẹran.” Samuẹli bá wí fún Jese, pé, “Ranṣẹ lọ pè é wá, nítorí pé a kò ní jókòó títí yóo fi dé.” Jese ranṣẹ lọ mú un wá. Ọmọ náà jẹ́ ọmọ pupa, ojú rẹ̀ dára ó sì lẹ́wà. OLUWA wí fún Samuẹli pé, “Dìde, kí o ta òróró sí i lórí nítorí pé òun ni mo yàn.” Nígbà náà ni Samuẹli mú ìwo tí òróró wà ninu rẹ̀, ó ta òróró náà sí i lórí láàrin àwọn arakunrin rẹ̀, Ẹ̀mí OLUWA sì bà lé Dafidi láti ọjọ́ náà lọ. Samuẹli bá gbéra, ó pada sí Rama. Ẹ̀mí OLUWA kúrò lára Saulu, ẹ̀mí burúkú láti ọ̀dọ̀ OLUWA sì ń dà á láàmú. Àwọn iranṣẹ Saulu wí fún un pé, “Wò ó! Ẹ̀mí burúkú láti ọ̀dọ̀ OLUWA ń dà ọ́ láàmú; fún àwa iranṣẹ rẹ tí a wà níwájú rẹ láṣẹ láti wá ọkunrin kan tí ó mọ hapu ta dáradára. Ìgbàkúùgbà tí ẹ̀mí burúkú láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun bá bà lé ọ, yóo máa fi hapu kọrin, ara rẹ yóo sì balẹ̀.” Saulu bá pàṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé kí wọ́n wá ọkunrin kan tí ó mọ hapu ta dáradára, kí wọ́n sì mú un wá siwaju òun. Ọ̀kan ninu àwọn ọdọmọkunrin náà dáhùn pé, “Wò ó! Mo ti rí ọmọ Jese ará Bẹtilẹhẹmu tí ó mọ hapu ta dáradára. Ó jẹ́ alágbára ati akọni lójú ogun, ó ní ọ̀rọ̀ rere lẹ́nu, ó lẹ́wà, OLUWA sì wà pẹlu rẹ̀.” Saulu bá ranṣẹ sí Jese pé kí ó fi Dafidi, ọmọ rẹ̀ tí ń tọ́jú agbo ẹran ranṣẹ sí òun. Jese di ẹrù burẹdi ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan, ati waini tí wọ́n rọ sinu ìgò aláwọ pẹlu ọmọ ewúrẹ́ kan, ó kó wọn rán Dafidi sí Saulu. Dafidi wá sọ́dọ̀ Saulu, ó sì ń bá a ṣiṣẹ́. Saulu fẹ́ràn rẹ̀ gidigidi, ó sì di ẹni tí ń ru ihamọra Saulu. Saulu ranṣẹ sí Jese, ó ní, “Jẹ́ kí Dafidi máa bá mi ṣiṣẹ́ nítorí ó ti bá ojurere mi pàdé.” Nígbàkúùgbà tí ẹ̀mí burúkú bá ti ọ̀dọ̀ OLUWA wá sórí Saulu, Dafidi a máa ta hapu fún un, ara Saulu á balẹ̀, ẹ̀mí burúkú náà a sì fi í sílẹ̀. Àwọn ọmọ ogun Filistini kó ara wọn jọ sí Soko, ìlú kan ní ilẹ̀ Juda láti bá Israẹli jagun. Wọ́n pa ibùdó wọn sí Efesi Damimu, tí ó wà láàrin Soko ati Aseka. Saulu ati àwọn ọmọ ogun Israẹli pa ibùdó tiwọn sí àfonífojì Ela, wọ́n sì múra ogun de àwọn ọmọ ogun Filistini. Àwọn Filistini dúró lórí òkè ní apá kan, àwọn Israẹli sì dúró lórí òkè ní apá keji. Àfonífojì kan sì wà láàrin wọn. Akikanju ọkunrin kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Goliati, ará ìlú Gati, jáde wá láti ààrin àwọn Filistini. Ó ga ní ìwọ̀n igbọnwọ mẹfa ati ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan. Ó dé àṣíborí bàbà, ó wọ ẹ̀wù tí wọ́n fi bàbà pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ẹẹdẹgbaata (5,000) ṣekeli. Ó ní ihamọra bàbà ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì gbé ọ̀kọ̀ bàbà kan sí èjìká rẹ̀. Ọ̀pá ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì dàbí igi òfì, irin tí ó wà lórí ọ̀kọ̀ rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹta (600) òṣùnwọ̀n ṣekeli. Ẹni tí ń ru asà rẹ̀ sì ń rìn níwájú rẹ̀. Goliati dúró, ó sì kígbe pe àwọn ọmọ Israẹli, ó ní, “Kí ló dé tí ẹ fi kó ara yín jọ láti jagun? Ṣebí Filistini kan ni èmi, ẹ̀yin náà sì jẹ́ ẹrú Saulu? Ẹ̀yin ẹ yan ọkunrin kan láàrin yín tí yóo sọ̀kalẹ̀ wá bá mi jà. Bí ó bá pa mí, a óo di ẹrú yín. Ṣugbọn bí mo bá ṣẹgun rẹ̀, tí mo sì pa á, ẹ óo di ẹrú wa. Mo pe ẹ̀yin ọmọ ogun Israẹli níjà lónìí, ẹ yan ọkunrin kan, kí ó wá bá mi jà.” Nígbà tí Saulu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbọ́, ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi. Ọmọ Jese ni Dafidi, ará Efurati ní Bẹtilẹhẹmu ti Juda; Ọmọkunrin mẹjọ ni Jese bí, ó sì ti di arúgbó nígbà tí Saulu jọba. Àwọn mẹta tí wọ́n dàgbà jùlọ láàrin àwọn ọmọ Jese bá Saulu lọ sójú ogun. Eliabu ni orúkọ àkọ́bí. Abinadabu ni ti ekeji, Ṣama sì ni ti ẹkẹta. Dafidi ni àbíkẹ́yìn patapata; àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ mẹta náà sì wà ninu àwọn ọmọ ogun Saulu. Dafidi a máa lọ sí Bẹtilẹhẹmu nígbà gbogbo láti tọ́jú agbo ẹran baba rẹ̀. Odidi ogoji ọjọ́ ni Goliati fi pe àwọn ọmọ ogun Israẹli níjà ní àràárọ̀ ati ìrọ̀lẹ́ ìrọ̀lẹ́. Ní ọjọ́ kan, Jese sọ fún Dafidi pé, “Jọ̀wọ́, mú ìwọ̀n efa àgbàdo yíyan kan, ati burẹdi mẹ́wàá yìí lọ fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ ní ibùdó ogun. Mú wàrà sísè mẹ́wàá yìí lọ́wọ́ fún olórí ogun ikọ̀ wọn, kí o sì bá mi wo alaafia àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ, kí o gba nǹkankan bọ̀ lọ́dọ̀ wọn tí yóo fihàn mí pé alaafia ni wọ́n wà.” Saulu ọba, ati àwọn ẹ̀gbọ́n Dafidi ati àwọn ọmọ ogun yòókù wà ní àfonífojì Ela níbi tí wọ́n ti ń bá àwọn Filistini jà. Dafidi dìde ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, ó fi ẹnìkan ṣọ́ agbo ẹran rẹ̀, ó mú oúnjẹ náà, ó sì lọ gẹ́gẹ́ bí Jese ti pàṣẹ fún un. Ó dé ibùdó ogun ní àkókò tí àwọn ọmọ ogun ń lọ sójú ogun, wọ́n ń hó ìhó ogun. Àwọn ọmọ ogun Israẹli ati ti Filistini dúró ní ipò wọn, wọ́n ń wo ara wọn. Dafidi fún olùtọ́jú ẹrù àwọn ọmọ ogun ní oúnjẹ tí ó gbé lọ, ó sì sáré tọ àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ sójú ogun láti kí wọn. Bí ó ti ń bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Goliati wá láti pe àwọn ọmọ ogun Israẹli níjà. Ó sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń sọ ọ́; Dafidi sì gbọ́. Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Israẹli rí Goliati, ẹ̀rù bà wọ́n; wọ́n sì sá lọ. Wọ́n ní, “Ẹ wo ọkunrin yìí, ẹ gbọ́ bí ó ti ń pe Israẹli níjà? Ọba sì ti sọ pé ẹni tí ó bá lè pa á yóo gba ẹ̀bùn lọpọlọpọ. Òun yóo sì fi ọmọbinrin òun fún olúwarẹ̀, ilé baba rẹ̀ yóo sì di òmìnira ní ilẹ̀ Israẹli: kò ní san owó orí mọ́.” Dafidi bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọkunrin náà pé, “Kí ni ọba ṣe ìlérí pé òun ó fún ẹni tí ó bá pa Filistini yìí, tí ó sì mú ẹ̀gàn kúrò lára Israẹli? Ta ni aláìkọlà Filistini yìí tí ń pẹ̀gàn àwọn ọmọ ogun Ọlọrun alààyè?” Àwọn ọkunrin náà sì sọ ohun tí ọba sọ pé òun yóo ṣe fún ẹni tí ó bá pa ọkunrin náà fún Dafidi. Nígbà tí Eliabu, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ àgbà gbọ́ tí ó ń bá àwọn ọkunrin náà sọ̀rọ̀, ó bínú sí Dafidi, ó ní, “Kí ni ìwọ ń wá níbí? Ta ni ó ń tọ́jú àwọn aguntan rẹ ninu pápá? Ìwọ onigbeeraga ati ọlọ́kàn líle yìí, nítorí kí o lè wo ogun ni o ṣe wá síbí.” Dafidi sì dáhùn pé, “Kí ni mo ṣe nisinsinyii? Ṣebí ọ̀rọ̀ lásán ni mò ń sọ.” Dafidi yipada kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ ẹlòmíràn, ó tún bèèrè ìbéèrè kan náà. Àwọn ọkunrin náà sì fún un ní èsì bíi ti iṣaaju. Àwọn ọmọ ogun náà sọ ọ̀rọ̀ tí Dafidi sọ níwájú Saulu, Saulu bá ranṣẹ pè é. Dafidi sọ fún Saulu pé, “Ẹ má bẹ̀rù ọkunrin yìí; èmi, iranṣẹ rẹ óo lọ bá a jà.” Saulu bá sọ fún Dafidi pé, “O kò lè bá Filistini yìí jà, nítorí pé ọmọde ni ọ́, òun sì ti jẹ́ jagunjagun láti ìgbà èwe rẹ̀ wá.” Dafidi dáhùn pé, “Ìgbàkúùgbà tí èmi iranṣẹ rẹ bá ń ṣọ́ agbo aguntan baba mi, tí kinniun tabi ẹranko beari bá gbé ọ̀kan ninu aguntan náà, n óo tẹ̀lé e lọ, n óo lù ú, n óo sì gba aguntan náà kúrò lẹ́nu rẹ̀. Bí ó bá sì kọjú ìjà sí mi, n óo di ọ̀fun rẹ̀ mú, n óo sì pa á. Èmi iranṣẹ rẹ yìí ti pa àwọn kinniun ati àwọn ẹranko beari rí, aláìkọlà Filistini yìí yóo sì dàbí ọ̀kan ninu wọn, nítorí pé, ó ti pe àwọn ọmọ ogun Ọlọrun alààyè níjà. OLUWA tí ó gbà mí lọ́wọ́ kinniun ati beari yóo gbà mí lọ́wọ́ Filistini yìí.” Saulu bá sọ fún Dafidi pé, “Máa lọ, OLUWA yóo wà pẹlu rẹ.” Saulu gbé ihamọra ogun rẹ̀ wọ Dafidi, ó fi àṣíborí idẹ kan dé e lórí, ó sì gbé ẹ̀wù tí a fi irin pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ ṣe wọ̀ ọ́. Dafidi di idà Saulu mọ́ ihamọra náà, ó sì gbìyànjú láti rìn, ṣugbọn kò lè rìn nítorí pé kò wọ ihamọra ogun rí. Dafidi sọ fún Saulu pé, “N kò lè lo ihamọra yìí, nítorí pé n kò wọ̀ ọ́ rí.” Dafidi bá tú wọn kúrò lára rẹ̀. Ó mú ọ̀pá darandaran rẹ̀, ó ṣa òkúta marun-un tí ń dán ninu odò, ó kó wọn sinu àpò rẹ̀, ó mú kànnàkànnà rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì lọ bá Filistini náà. Filistini náà sì ń rìn bọ̀ wá pàdé Dafidi; ẹni tí ń ru asà rẹ̀ sì wà níwájú rẹ̀. Nígbà tí ó rí Dafidi dáradára, ó wò ó pé ọmọ kékeré kan lásán, tí ó tóbi tí ó sì lẹ́wà ni, nítorí náà, ó fojú tẹmbẹlu rẹ̀. Ó bi Dafidi pé, “Ṣé ajá ni mí ni, tí o fi ń mú ọ̀pá tọ̀ mí bọ̀?” Ó fi Dafidi bú ní orúkọ oriṣa rẹ̀, ó sì wí pé, “Sún mọ́ mi níhìn-ín, n óo sì fi ẹran ara rẹ fún àwọn ẹyẹ ati ẹranko jẹ.” Dafidi dáhùn pé, “Ìwọ ń bọ̀ wá bá mi jà pẹlu idà ati ọ̀kọ̀, ṣugbọn èmi ń bọ̀ wá pàdé rẹ ní orúkọ OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun Israẹli, tí ò ń pẹ̀gàn. Lónìí yìí ni OLUWA yóo fà ọ́ lé mi lọ́wọ́, n óo pa ọ́, n óo gé orí rẹ, n óo sì fi òkú àwọn ọmọ ogun Filistini fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ati ẹranko ìgbẹ́. Gbogbo ayé yóo sì mọ̀ pé Ọlọrun wà fún Israẹli. Gbogbo àwọn eniyan wọnyi yóo sì mọ̀ dájú pé OLUWA kò nílò idà ati ọ̀kọ̀ láti gba eniyan là. Ti OLUWA ni ogun yìí, yóo sì gbé mi borí rẹ̀.” Bí Filistini náà ṣe ń bọ̀ láti pàdé Dafidi, Dafidi sáré sí ààlà ogun láti pàdé rẹ̀. Dafidi mú òkúta kan jáde láti inú àpò rẹ̀, ó fi kànnàkànnà rẹ̀ ta òkúta náà, òkúta náà wọ agbárí Goliati lọ, ó sì ṣubú lulẹ̀. Dafidi ṣẹgun Filistini náà láìní idà lọ́wọ́; kànnàkànnà ati òkúta ni ó fi pa á. Dafidi sáré sí Goliati, ó yọ idà Goliati kúrò ninu àkọ̀, ó sì fi gé orí rẹ̀. Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Filistini rí i pé akikanju àwọn ti kú, wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ. Àwọn ọmọ ogun Israẹli ati ti Juda hó ìhó ogun, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn Filistini lọ. Wọ́n lé wọn títí dé Gati ati dé ẹnu ibodè Ekironi. Àwọn Filistini tí wọ́n fara gbọgbẹ́ sì ṣubú láti Ṣaaraimu títí dé Gati ati Ekironi. Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Israẹli pada dé, wọ́n lọ kó ìkógun ninu ibùdó àwọn ọmọ ogun Filistini. Dafidi gbé orí ati ihamọra Goliati; ó gbé orí rẹ̀ lọ sí Jerusalẹmu, ṣugbọn ó kó ihamọra rẹ̀ sinu àgọ́ tirẹ̀. Nígbà tí Saulu rí Dafidi tí ó ń lọ bá Goliati jà, ó bèèrè lọ́wọ́ Abineri, olórí ogun rẹ̀ pé, “Ọmọ ta ni ọmọkunrin yìí?” Abineri dá a lóhùn pé, “Kabiyesi, n kò mọ̀.” Ọba pàṣẹ fún un pé kí ó wádìí ọmọ ẹni tí ọmọ náà í ṣe. Nígbà tí Dafidi pada sí ibùdó lẹ́yìn tí ó ti pa Goliati, Abineri mú un lọ siwaju Saulu, pẹlu orí Goliati ní ọwọ́ rẹ̀. Saulu bi í léèrè pé, “Ọmọ, ta ni baba rẹ?” Dafidi dáhùn pé, “Ọmọ Jese ni mí, iranṣẹ rẹ, tí ń gbé Bẹtilẹhẹmu.” Lẹ́yìn tí Dafidi ati Saulu parí ọ̀rọ̀ wọn, ọkàn Jonatani, ọmọ Saulu fà mọ́ Dafidi lọpọlọpọ ó sì fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí ara rẹ̀. Saulu gba Dafidi sọ́dọ̀ ní ọjọ́ náà, kò sì jẹ́ kí ó pada sílé baba rẹ̀. Jonatani bá bá Dafidi dá majẹmu, nítorí pé ó fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí ara rẹ̀. Ó bọ́ aṣọ tí ó wọ̀ fún Dafidi, ó sì kó ihamọra rẹ̀ pẹlu idà ati ọfà ati àmùrè rẹ̀ fún un. Dafidi ń ṣe àṣeyọrí ninu àwọn iṣẹ́ tí Saulu ń rán an. Nítorí náà, Saulu fi ṣe ọ̀kan ninu àwọn olórí ogun rẹ̀. Èyí sì tẹ́ àwọn olórí yòókù lọ́rùn. Bí wọ́n ti ń pada bọ̀ wálé, lẹ́yìn tí Dafidi ti pa Goliati, àwọn obinrin jáde láti gbogbo ìlú Israẹli, wọ́n lọ pàdé Saulu ọba, pẹlu orin ati ijó, wọ́n ń lu aro, wọ́n sì ń kọrin ayọ̀ pẹlu àwọn ohun èlò orin. Bí wọ́n ti ń jó, wọ́n ń kọrin báyìí pé, “Saulu pa ẹgbẹẹgbẹrun tirẹ̀, ṣugbọn Dafidi pa ẹgbẹẹgbaarun tirẹ̀.” Inú Saulu kò dùn sí orin tí wọ́n ń kọ, inú sì bí i gidigidi. Ó ní, “Wọ́n fún Dafidi ní ẹgbẹẹgbaarun ṣugbọn wọ́n fún mi ní ẹgbẹẹgbẹrun, kí ló kù tí wọn óo fún un ju ìjọba mi lọ.” Láti ọjọ́ náà ni Saulu ti ń ṣe ìlara Dafidi. Ní ọjọ́ keji, ẹ̀mí burúkú láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun bà lé Saulu, ó sì ń sọ kántankàntan láàrin ilé rẹ̀. Dafidi bẹ̀rẹ̀ sí ta hapu fún un gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ọ̀kọ̀ kan wà lọ́wọ́ Saulu. Ó ju ọ̀kọ̀ náà, ó ní kí òun fi gún Dafidi ní àgúnmọ́ ògiri. Ó ju ọ̀kọ̀ náà nígbà meji, ṣugbọn Dafidi yẹ̀ ẹ́ lẹẹmejeeji. Saulu bẹ̀rù Dafidi nítorí pé OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ṣugbọn OLUWA kọ òun sílẹ̀. Saulu mú un kúrò lọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó fi ṣe olórí ẹgbẹrun ọmọ ogun, Dafidi sì ń darí àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ó ń ṣe àṣeyọrí nítorí pé OLUWA wà pẹlu rẹ̀. Saulu tún bẹ̀rù Dafidi sí i nítorí àwọn àṣeyọrí rẹ̀. Ṣugbọn gbogbo àwọn ará Israẹli ati Juda ni wọ́n fẹ́ràn Dafidi, nítorí ó jẹ́ olórí tí ń ṣe àṣeyọrí. Saulu sọ fún Dafidi pé, “Merabu ọmọbinrin mi àgbà nìyí, n óo fún ọ kí o fi ṣe aya, ṣugbọn o óo jẹ́ ọmọ ogun mi, o óo sì máa ja ogun OLUWA.” Nítorí Saulu rò ninu ara rẹ̀ pé, àwọn Filistini ni yóo pa Dafidi, òun kò ní fi ọwọ́ ara òun pa á. Dafidi dáhùn pé, “Ta ni èmi ati ìdílé baba mi tí n óo fi di àna ọba?” Ṣugbọn nígbà tí ó tó àkókò tí ó yẹ kí Saulu fi Merabu fún Dafidi, Adirieli ará Mehola ni ó fún. Ṣugbọn Mikali ọmọbinrin Saulu nífẹ̀ẹ́ Dafidi; nígbà tí Saulu gbọ́, inú rẹ̀ dùn sí i. Ó wí ninu ara rẹ̀ pé, “N óo fi Mikali fún Dafidi kí ó lè jẹ́ ìdẹkùn fún un, àwọn Filistini yóo sì rí i pa.” Saulu ṣèlérí fún Dafidi lẹẹkeji pé, “O óo di àna mi.” Saulu pàṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ẹ lọ bá Dafidi sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀ pé, inú ọba dùn sí i lọpọlọpọ, ati pé gbogbo àwọn iranṣẹ ọba fẹ́ràn rẹ̀, nítorí náà ó yẹ kí ó fẹ́ ọmọ ọba.” Nígbà tí wọ́n sọ èyí fún Dafidi, ó dá wọn lóhùn pé, “Kì í ṣe nǹkan kékeré ni láti jẹ́ àna ọba, talaka ni mí, èmi kì í sì í ṣe eniyan pataki.” Àwọn iranṣẹ náà sọ èsì tí Dafidi fún wọn fún Saulu. Saulu sì rán wọn pé kí wọ́n sọ fún Dafidi pé, “Ọba kò bèèrè ẹ̀bùn igbeyawo kankan lọ́wọ́ rẹ ju ọgọrun-un awọ orí adọ̀dọ́ àwọn ará Filistia, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀san lára àwọn ọ̀tá ọba.” Saulu rò pé àwọn ará Filistia yóo tipa bẹ́ẹ̀ pa Dafidi. Nígbà tí àwọn iranṣẹ Saulu jíṣẹ́ fún Dafidi, inú rẹ̀ dùn, ó sì gbà láti di àna ọba. Kí ó tó di ọjọ́ igbeyawo, Dafidi ati àwọn jagunjagun rẹ̀ lọ pa igba (200) Filistini, ó sì kó awọ adọ̀dọ́ wọn wá fún ọba, kí ó lè fẹ́ ọmọ ọba. Saulu sì fi ọmọbinrin rẹ̀, Mikali, fún Dafidi. Saulu rí i dájúdájú pé OLUWA wà pẹlu Dafidi ati pé Mikali ọmọ òun fẹ́ràn Dafidi. Nítorí náà, ó bẹ̀rù Dafidi sí i, ó sì ń bá Dafidi ṣe ọ̀tá títí gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. Ninu gbogbo ogun tí wọ́n bá àwọn ara Filistia jà, Dafidi ní ìṣẹ́gun ju gbogbo àwọn olórí ogun Saulu yòókù lọ. Ó sì jẹ́ olókìkí láàrin wọn. Saulu sọ fún ọmọ rẹ̀ Jonatani ati gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé kí wọ́n pa Dafidi. Ṣugbọn Jonatani fẹ́ràn Dafidi lọpọlọpọ. Ó sì sọ fún Dafidi pé, “Baba mi fẹ́ pa ọ́, nítorí náà fi ara pamọ́ sí ibi kọ́lọ́fín kan lọ́la, kí o má ṣe wá sí gbangba. N óo dúró pẹlu baba mi ní orí pápá lọ́la níbi tí o bá farapamọ́ sí, n óo sì bá a sọ̀rọ̀ nípa rẹ, ohunkohun tí mo bá sì gbọ́ lẹ́nu rẹ̀, n óo sọ fún ọ.” Jonatani sọ̀rọ̀ Dafidi ní rere níwájú Saulu, ó wí pé, “Kabiyesi, má ṣe nǹkankan burúkú sí iranṣẹ rẹ, Dafidi, nítorí kò ṣe ibi kan sí ọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbogbo nǹkan tí ń ṣe ni ó ń jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún ọ. Ó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wéwu láti pa Goliati, OLUWA sì ṣẹ́ ogun ńlá fún Israẹli. Nígbà tí o rí i inú rẹ dùn. Kí ló dé tí o fi ń wá ọ̀nà láti pa Dafidi láìṣẹ̀?” Saulu gbọ́rọ̀ sí Jonatani lẹ́nu, ó sì búra ní orúkọ OLUWA pé, “Bí OLUWA ti ń bẹ, n kò ní pa á.” Jonatani pe Dafidi ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà fún un. Ó mú Dafidi wá siwaju ọba, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ iranṣẹ fún ọba bíi ti àtẹ̀yìnwá. Ogun tún bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn Filistini ati Israẹli. Dafidi kọlu àwọn Filistini, ó pa pupọ ninu wọn tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn Filistini fi sá lójú ogun. Ní ọjọ́ kan, ẹ̀mí burúkú láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun tún bà lé Saulu, bí ó ti jókòó ninu ilé rẹ̀ tí ó mú ọ̀kọ̀ lọ́wọ́, tí Dafidi sì ń lu dùùrù níwájú rẹ̀, Saulu ju ọ̀kọ̀ náà, ó ní kí òun fi gún Dafidi mọ́ ògiri, ṣugbọn Dafidi yẹ̀ ẹ́, ọ̀kọ̀ náà wọ ara ògiri, Dafidi bá sá lọ. Ní alẹ́ ọjọ́ náà, Saulu rán àwọn iranṣẹ kan láti máa ṣọ́ ilé Dafidi kí wọ́n lè pa á ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji. Ṣugbọn Mikali iyawo rẹ̀ sọ fún Dafidi pé, “Sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ ní alẹ́ yìí, nítorí pé bí o bá di ọ̀la níbí, wọn yóo pa ọ́.” Mikali bá sọ Dafidi kalẹ̀ láti ojú fèrèsé kan, ó sì sá lọ láti fi ara pamọ́. Mikali sì mú ère kan, ó tẹ́ ẹ sórí ibùsùn, ó gbé ìrọ̀rí onírun ewúrẹ́ sibẹ, ó fi ṣe ìrọ̀rí rẹ̀, ó sì fi aṣọ bò ó. Nígbà tí àwọn iranṣẹ Saulu dé láti mú Dafidi, Mikali sọ fún wọn pé, “Ara rẹ̀ kò yá.” Saulu tún rán àwọn iranṣẹ náà lọ wo Dafidi, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gbé e wá fún mi ti òun ti ibùsùn rẹ̀, kí n pa á.” Nígbà tí àwọn iranṣẹ náà dé, wọ́n bá ère ní orí ibùsùn pẹlu ìrọ̀rí onírun ewúrẹ́ ní ìgbèrí rẹ̀. Saulu sì bèèrè lọ́wọ́ Mikali pé, “Kí ló dé tí o fi tàn mí, tí o sì jẹ́ kí ọ̀tá mi sá àsálà?” Mikali dá Saulu lóhùn pé, “Ó sọ wí pé òun yóo pa mí bí n kò bá jẹ́ kí òun sá lọ.” Dafidi sá àsálà, ó sá lọ sí ọ̀dọ̀ Samuẹli ní Rama, ó sọ gbogbo ohun tí Saulu ti ṣe sí i fún un. Òun pẹlu Samuẹli sì lọ ń gbé Naioti. Nígbà tí Saulu gbọ́ pé Dafidi wà ní Naioti ní Rama, ó rán àwọn iranṣẹ láti mú un. Nígbà tí àwọn iranṣẹ náà rí ẹgbẹ́ àwọn wolii tí wọn ń jó, tí wọ́n sì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀, pẹlu Samuẹli ní ààrin wọn gẹ́gẹ́ bí olórí wọn, ẹ̀mí Ọlọrun bà lé àwọn iranṣẹ náà, àwọn náà bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀. Nígbà tí Saulu gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn oníṣẹ́ rẹ̀, ó rán àwọn mìíràn, àwọn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀. Ó rán àwọn oníṣẹ́ ní ìgbà kẹta, àwọn náà tún ń sọ àsọtẹ́lẹ̀. Òun pàápàá dìde ó lọ sí Rama. Nígbà tí ó dé etí kànga jíjìn tí ó wà ní Seku, ó bèèrè ibi tí Samuẹli ati Dafidi wà. Wọ́n sì sọ fún un wí pé, wọ́n wà ní Naioti ti Rama. Ó kúrò níbẹ̀, ó sì lọ sí Naioti ti Rama, bí ó ti ń lọ, ẹ̀mí Ọlọrun bà lé e, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀ títí tí ó fi dé Naioti. Ó bọ́ aṣọ rẹ̀, ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ níwájú Samuẹli. Ó sùn ní ìhòòhò ní ọ̀sán ati òru ọjọ́ náà. Àwọn eniyan sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ wí pé, “Àbí Saulu náà ti di wolii?” Dafidi sá kúrò ní Naioti, ní Rama, lọ sọ́dọ̀ Jonatani, ó sì bi í pé, “Kí ni mo ṣe? Ìwà burúkú wo ni mo hù? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ baba rẹ tí ó fi ń wọ́nà láti pa mí?” Jonatani dá a lóhùn pé, “Kí á má rí i, o kò ní kú. Kò sí nǹkankan ti baba mi ń ṣe, bóyá ńlá tabi kékeré, tí kì í sọ fún mi; kò sì tíì sọ èyí fún mi, nítorí náà ọ̀rọ̀ náà kò rí bẹ́ẹ̀.” Dafidi dáhùn pé, “Baba rẹ mọ̀ wí pé bí òun bá sọ fún ọ, inú rẹ kò ní dùn, nítorí pé o fẹ́ràn mi. Nítòótọ́ bí OLUWA tí ń bẹ láàyè, tí ẹ̀mí rẹ náà sì ń bẹ láàyè, ìṣísẹ̀ kan ló wà láàrin èmi ati ikú.” Jonatani bá dáhùn pé, “N óo ṣe ohunkohun tí o bá fẹ́.” Dafidi sọ fún un pé, “Ọ̀la ni ọjọ́ àjọ̀dún oṣù tuntun, n kò sì gbọdọ̀ má bá ọba jókòó jẹun. Ṣugbọn jẹ́ kí n lọ farapamọ́ sinu pápá títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹta. Bí baba rẹ bá bèèrè mi, sọ fún un pé mo ti gbààyè lọ́wọ́ rẹ láti lọ sí ìlú mi, ní Bẹtilẹhẹmu, nítorí pé àkókò yìí jẹ́ àkókò fún àjọ̀dún ẹbọ ọdọọdún ìdílé wa. Bí ó bá sọ pé kò burú, a jẹ́ wí pé alaafia ni fún iranṣẹ rẹ, ṣugbọn bí ó bá bínú gidigidi, èyí yóo fihàn ọ́ wí pé, ó ní ìpinnu burúkú sí mi. Nítorí náà ṣe èmi iranṣẹ rẹ ní oore kan, nítorí o ti mú mi dá majẹmu mímọ́ pẹlu rẹ. Ṣugbọn bí o bá rí ohun tí ó burú ninu ìwà mi, ìwọ gan-an ni kí o pa mí; má wulẹ̀ fà mí lé baba rẹ lọ́wọ́ láti pa.” Jonatani bá dáhùn wí pé, “Má ṣe ní irú èrò bẹ́ẹ̀ lọ́kàn. Ṣé mo lè mọ̀ dájú pé baba mi fẹ́ pa ọ́, kí n má sọ fún ọ?” Dafidi bá bèèrè pé, “Báwo ni n óo ṣe mọ̀ bí baba rẹ bá bínú?” Jonatani dáhùn pé, “Máa bọ̀, jẹ́ kí á lọ sinu pápá.” Àwọn mejeeji sì lọ. Jonatani sọ fún Dafidi pé, “Kí OLUWA Ọlọrun Israẹli ṣe ẹlẹ́rìí láàrin èmi pẹlu rẹ. Ní àkókò yìí lọ́la tabi ní ọ̀tunla n óo wádìí nípa rẹ̀ lọ́wọ́ baba mi. Bí inú rẹ̀ bá yọ́ sí ọ n óo ranṣẹ sí ọ. Ṣugbọn bí ó bá ń gbèrò láti ṣe ọ́ níbi, kí OLUWA ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi ati jù bẹ́ẹ̀ lọ, kí OLUWA pa mí bí n kò bá sọ fún ọ, kí n sì ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sá àsálà. Kí OLUWA wà pẹlu rẹ bí ó ti ṣe wà pẹlu baba mi. Bí mo bá sì wà láàyè kí o fi ìfẹ́ òtítọ́ OLUWA hàn sí mi kí n má baà kú. Ṣugbọn bí mo bá kú, má jẹ́ kí àánú rẹ kúrò ninu ilé mi títí lae. Nígbà tí OLUWA bá ti ké gbogbo àwọn ọ̀tá Dafidi kúrò lórí ilẹ̀ ayé, má jẹ́ kí orúkọ Jonatani di ìkékúrò ní ilé Dafidi. Kí OLUWA gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá Dafidi.” Jonatani tún mú kí Dafidi ṣe ìbúra lẹ́ẹ̀kan sí i, pẹlu ìfẹ́ tí ó ní sí i. Nítorí pé, Jonatani fẹ́ràn rẹ̀ bí ó ti fẹ́ràn ẹ̀mí ara rẹ̀. Lẹ́yìn náà, Jonatani sọ fún Dafidi pé, “Ọ̀la ni ọjọ́ àjọ̀dún oṣù tuntun, àwọn eniyan yóo sì mọ̀ bí o kò bá wá síbi oúnjẹ nítorí ààyè rẹ yóo ṣófo. Bí wọn kò bá rí ọ ní ọjọ́ keji, wọn yóo mọ̀ dájú pé o kò sí láàrin wọn. Nítorí náà, lọ sí ibi tí o farapamọ́ sí ní ìjelòó, kí o sì farapamọ́ sẹ́yìn àwọn òkúta ọ̀hún nnì. N óo sì ta ọfà mẹta sí ìhà ibẹ̀ bí ẹni pé mo ta wọ́n sí àmì kan. N óo rán ọmọkunrin kan láti wá àwọn ọfà náà. Bí mo bá sọ fún un pé, ‘Wò ó àwọn ọfà náà wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,’ kí o jáde wá, nítorí bí OLUWA tí ń bẹ, kò sí ewu kankan fún ọ. Ṣugbọn bí mo bá sọ fún un pé, ‘Wo àwọn ọfà náà níwájú rẹ,’ máa bá tìrẹ lọ nítorí OLUWA ni ó fẹ́ kí o lọ. Nípa ọ̀rọ̀ tí èmi pẹlu rẹ jọ sọ, ranti pé OLUWA wà láàrin wa laelae.” Dafidi farapamọ́ ninu pápá, ní ọjọ́ àjọ̀dún oṣù tuntun, Saulu ọba jókòó láti jẹun. Ọba jókòó níbi tí ó máa ń jókòó sí ní ẹ̀gbẹ́ ògiri, Jonatani jókòó ní iwájú rẹ̀. Abineri sì jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ Saulu. Ṣugbọn ààyè Dafidi ṣófo. Sibẹ Saulu kò sọ nǹkankan nítorí pé ó rò pé bóyá nǹkankan ti ṣẹlẹ̀ sí Dafidi, tí ó sì sọ ọ́ di aláìmọ́ ni. Ní ọjọ́ keji àjọ̀dún oṣù tuntun, ìjókòó Dafidi tún ṣófo. Nígbà náà ni Saulu bèèrè lọ́wọ́ Jonatani pé, “Kí ló dé tí ọmọ Jese kò wá sí ibi oúnjẹ lánàá ati lónìí?” Jonatani dáhùn pé, “Ó gbààyè lọ́wọ́ mi láti lọ sí Bẹtilẹhẹmu. Ó sọ pé, àwọn ẹ̀gbọ́n òun ti pa á láṣẹ fún òun láti wá sí ibi àjọ̀dún ẹbọ ọdọọdún ti ìdílé wọn. Ó sì tọrọ ààyè lọ́wọ́ mi pé òun fẹ́ wà pẹlu àwọn ìdílé òun ní àkókò àjọ̀dún náà. Òun ni kò fi lè wá síbi àsè ọba.” Inú bí Saulu gidigidi sí Jonatani, ó ní, “Ìwọ ọmọ ọlọ̀tẹ̀ ati aláìgbọràn obinrin yìí, mo mọ̀ wí pé ò ń gbè lẹ́yìn Dafidi, o sì ń ta àbùkù ara rẹ ati ìhòòhò ìyá rẹ. Ṣé o kò mọ̀ wí pé níwọ̀n ìgbà tí ọmọ Jese bá wà láàyè, o kò lè jọba ní Israẹli kí ìjọba rẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀? Yára nisinsinyii kí o ranṣẹ lọ mú un wá; dandan ni kí ó kú.” Jonatani sì dáhùn pé, “Kí ló dé tí yóo fi kú? Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀?” Saulu bá ju ọ̀kọ̀ rẹ̀ mọ́ ọn, ó fẹ́ pa á. Nígbà náà ni Jonatani mọ̀ dájú pé, baba òun pinnu láti pa Dafidi. Jonatani sì fi ibinu dìde kúrò ní ìdí tabili oúnjẹ, kò sì jẹun ní ọjọ́ náà, tíí ṣe ọjọ́ keji oṣù. Inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi fún Dafidi, nítorí pé baba rẹ̀ dójú tì í. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, Jonatani mú ọmọde kan lọ́wọ́, ó lọ sí orí pápá gẹ́gẹ́ bí àdéhùn òun ati Dafidi. Ó sọ fún ọmọ náà pé, “Sáré lọ wá àwọn ọfà tí mo ta wá.” Bí ọmọ náà ti ń sáré lọ, Jonatani ta ọfà siwaju rẹ̀. Nígbà tí ọmọ náà dé ibi tí ọfà náà balẹ̀ sí, Jonatani pè é, ó ní, “Ọfà náà wà níwájú rẹ,” Jonatani tún sọ fún un pe, “Yára má ṣe dúró.” Ọmọ náà ṣa àwọn ọfà náà, ó sì pada sọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀, kò mọ nǹkankan; Jonatani ati Dafidi nìkan ni wọ́n mọ ìtumọ̀ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀. Jonatani kó àwọn ohun ìjà rẹ̀ fún ọmọ náà pé kí ó kó wọn lọ sílé. Bí ọmọ náà ti lọ tán, ni Dafidi jáde láti ibi òkúta tí ó sápamọ́ sí, ó sì dojúbolẹ̀, ó tẹríba lẹẹmẹta. Àwọn mejeeji sì fi ẹnu ko ara wọn lẹ́nu, wọn sọkún títí tí ara Dafidi fi wálẹ̀. Lẹ́yìn náà ni Jonatani sọ fún Dafidi pé, “Kí Ọlọrun wà pẹlu rẹ. Kí OLUWA ran àwa mejeeji lọ́wọ́ ati àwọn ọmọ wa, kí á lè pa majẹmu tí ó wà láàrin wa mọ́ laelae.” Lẹ́yìn tí Dafidi lọ, Jonatani pada sí ààrin ìlú. Dafidi lọ sọ́dọ̀ Ahimeleki alufaa, ní Nobu. Ahimeleki sì jáde pẹlu ìbẹ̀rù láti pàdé rẹ̀, ó sì bi í pé, “Ṣé kò sí nǹkan tí ìwọ nìkan fi dá wá, tí kò sí ẹnikẹ́ni pẹlu rẹ?” Ó dáhùn pé, “Ọba ni ó rán mi ní iṣẹ́ pataki kan, ó sì ti sọ fún mi pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ mọ̀ nípa iṣẹ́ tí òun rán mi. Mo sì ti sọ fún àwọn iranṣẹ mi pé kí wọ́n pàdé mi ní ibìkan. Kí ni ẹ ní lọ́wọ́? Fún mi ní ìṣù burẹdi marun-un tabi ohunkohun tí o bá ní.” Alufaa náà sì dáhùn pé, “N kò ní burẹdi lásán, àfi èyí tí ó jẹ́ mímọ́. Mo lè fún ọ tí ó bá dá ọ lójú pé àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ ti pa ara wọn mọ́, tí wọn kò sì bá obinrin lòpọ̀.” Dafidi dáhùn pé, “Àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu mi a máa pa ara wọn mọ́ nígbà tí a bá ń lọ fún iṣẹ́ tí kò ṣe pataki, kí á tó wá sọ ti iṣẹ́ yìí, tí ó jẹ́ iṣẹ́ pataki?” Alufaa kó àwọn burẹdi mímọ́ náà fún Dafidi, nítorí pé kò sí òmíràn níbẹ̀, àfi burẹdi ìfihàn tí wọ́n kó kúrò níwájú OLUWA láti fi òmíràn rọ́pò rẹ̀. Doegi, olórí darandaran Saulu, ará Edomu wà níbẹ̀ ní ọjọ́ náà, nítorí pé ó ń jọ́sìn níwájú OLUWA. Dafidi tún bèèrè lọ́wọ́ Ahimeleki pé, “Ǹjẹ́ o ní ọ̀kọ̀ tabi idà kí o fún mi? Ìkánjú tí mo fi kúrò nílé kò jẹ́ kí n ranti mú idà tabi ohun ìjà kankan lọ́wọ́.” Ahimeleki sì dáhùn pé, “Idà Goliati ará Filistia tí o pa ní àfonífojì Ela nìkan ni ó wà ní ibí. A fi aṣọ kan wé e sí ẹ̀yìn efodu. Bí o bá fẹ́, o lè mú un. Kò sì sí òmíràn níbí lẹ́yìn rẹ̀.” Dafidi dáhùn pé, “Kò sí idà tí ó dàbí rẹ̀, mú un fún mi.” Dafidi sá fún Saulu ní ọjọ́ náà. Ó sì lọ sọ́dọ̀ Akiṣi, ọba Gati. Àwọn iranṣẹ Akiṣi sì sọ fún un pé, “Ǹjẹ́ Dafidi, ọba ilẹ̀ rẹ̀ kọ́ nìyí, tí àwọn obinrin ń kọrin nípa rẹ̀ pé: ‘Saulu pa ẹgbẹrun tirẹ̀, Dafidi sì pa ẹgbẹẹgbaarun tirẹ̀?’ ” Dafidi fi àwọn ọ̀rọ̀ wọnyi sọ́kàn ó ṣe bí ẹni pé kò mọ ohun tí wọn ń sọ, ṣugbọn ó bẹ̀rù Akiṣi, ọba Gati gidigidi. Ó yí ìṣe rẹ̀ pada níwájú wọn, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bíi wèrè. Ó ń fi ọwọ́ ha ìlẹ̀kùn ojú ọ̀nà ààfin, ó sì ń wa itọ́ sí irùngbọ̀n rẹ̀. Akiṣi bá sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ẹ kò rí i pé aṣiwèrè ni ọkunrin yìí ni, kí ló dé tí ẹ mú un wá sọ́dọ̀ mi? Ṣé n kò ní aṣiwèrè níhìn-ín ni, tí ẹ fi mú un wá siwaju mi kí ó wá ṣe wèrè rẹ̀? Ǹjẹ́ irú ọkunrin yìí ni ó yẹ kí ó wá sinu ilé mi?” Dafidi sá kúrò ní ìlú Gati, lọ sinu ihò òkúta kan lẹ́bàá Adulamu. Nígbà tí àwọn arakunrin rẹ̀ ati ìdílé baba rẹ̀ gbọ́, wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ninu ìpọ́njú, ati àwọn tí wọ́n jẹ gbèsè ati àwọn tí wọ́n wà ninu ìbànújẹ́ sá wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Gbogbo wọn jẹ́ irinwo (400) ọkunrin, ó sì jẹ́ olórí wọn. Dafidi kúrò níbẹ̀ lọ sí Misipa ní ilẹ̀ Moabu, ó sọ fún ọba Moabu pé, “Jọ̀wọ́ jẹ́ kí baba ati ìyá mi dúró lọ́dọ̀ rẹ títí tí n óo fi mọ ohun tí Ọlọrun yóo ṣe fún mi.” Dafidi fi àwọn òbí rẹ̀ sílẹ̀ lọ́dọ̀ ọba Moabu, wọ́n sì wà níbẹ̀ ní gbogbo ìgbà tí Dafidi wà ní ìpamọ́. Wolii Gadi sọ fún Dafidi pé, “Má dúró níbi ìpamọ́ yìí mọ́, múra, kí o lọ sí ilẹ̀ Juda.” Dafidi bá lọ sí igbó Hereti. Nígbà tí Saulu jókòó ní abẹ́ igi tamarisiki ní orí òkè kan ni Gibea, ọ̀kọ̀ rẹ̀ wà ní ọwọ́ rẹ̀, àwọn olórí ogun rẹ̀ sì dúró yí i ká, ó gbọ́ pé wọ́n rí Dafidi ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sí àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀; ó ní, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ará Bẹnjamini, ṣé ọmọ Jese yìí yóo fún olukuluku yín ní oko ati ọgbà àjàrà? Ṣé yóo sì fi olukuluku yín ṣe olórí àwọn ọmọ ogun rẹ̀? Ṣé nítorí náà ni ẹ ṣe gbìmọ̀ burúkú sí mi, tí ẹnikẹ́ni ninu yín kò fi sọ fún mi pé ọmọ mi bá ọmọ Jese dá majẹmu. Bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò sì káàánú mi láàrin yín, kí ó sì sọ fún mi pé, ọmọ mi ń ran iranṣẹ mi lọ́wọ́ láti ba dè mí, bí ọ̀rọ̀ ti rí lónìí yìí.” Doegi ará Edomu, tí ó dúró láàrin àwọn olórí ogun Saulu dáhùn pé, “Mo rí Dafidi nígbà tí ó lọ sọ́dọ̀ Ahimeleki ọmọ Ahitubu ní Nobu. Ahimeleki bá a ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ OLUWA, lẹ́yìn náà ó fún Dafidi ní oúnjẹ ati idà Goliati, ará Filistia.” Nítorí náà Saulu ọba ranṣẹ pe Ahimeleki ati gbogbo ìdílé rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ alufaa ní Nobu, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Saulu ní, “Gbọ́ mi! Ìwọ ọmọ Ahitubu.” Ó dáhùn pé, “Mò ń gbọ́, oluwa mi.” Saulu bi í pé, “Kí ló dé tí ìwọ ati ọmọ Jese fi gbìmọ̀ burúkú sí mi? Tí o fún un ní oúnjẹ ati idà, tí o sì tún bá a ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ Ọlọrun. Dafidi ti lòdì sí mi báyìí, ó sì ti ba dè mí, láti pa mí.” Ahimeleki dáhùn pé, “Ta ló jẹ́ olóòótọ́ bíi Dafidi láàrin gbogbo àwọn olórí ogun rẹ? Ṣebí àna rẹ ni, ó sì jẹ́ olórí àwọn ọmọ ogun tí wọn ń ṣọ́ ọ ati eniyan pataki ninu ilé rẹ. Ǹjẹ́ èyí ha ni ìgbà àkọ́kọ́ tí mo bá a ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ Ọlọ́run? Rárá o! Nítorí náà kí ọba má ṣe ka ẹ̀sùn kankan sí èmi ati ìdílé baba mi lẹ́sẹ̀, nítorí pé, èmi iranṣẹ rẹ, kò mọ nǹkankan nípa ọ̀tẹ̀ tí Dafidi dì sí ọ.” Ọba dáhùn pé, “Ahimeleki, ìwọ ati ìdílé baba rẹ yóo kú.” Ọba bá pàṣẹ fún àwọn ọmọ ogun tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ pa àwọn alufaa OLUWA nítorí pé wọ́n wà lẹ́yìn Dafidi, wọ́n mọ̀ pé ó ń sá lọ, wọn kò sì sọ fún mi.” Ṣugbọn àwọn ọmọ ogun náà kọ̀ láti pa àwọn alufaa OLUWA. Ọba bá pàṣẹ fún Doegi pé, “Ìwọ, lọ pa wọ́n.” Doegi ará Edomu sì pa alufaa marunlelọgọrin, tí ń wọ aṣọ efodu. Saulu pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn tí wọn ń gbé Nobu, ìlú àwọn alufaa, atọkunrin atobinrin, àtọmọdé, àtọmọ ọwọ́, ati mààlúù, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ati aguntan, wọ́n sì pa gbogbo wọn. Ṣugbọn Abiatari, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Ahimeleki sá àsálà, ó sì lọ sọ́dọ̀ Dafidi. Ó sọ fún un bí Saulu ṣe pa àwọn alufaa OLUWA. Dafidi dá a lóhùn pé, “Nígbà tí mo ti rí Doegi níbẹ̀ ní ọjọ́ náà ni mo ti fura pé yóo sọ fún Saulu. Nítorí náà, ẹ̀bi ikú àwọn eniyan rẹ wà lọ́rùn mi. Dúró tì mí, má sì ṣe bẹ̀rù, nítorí pé Saulu tí ó fẹ́ pa ọ́, fẹ́ pa èmi pàápàá, ṣugbọn o óo wà ní abẹ ààbò níbí.” Nígbà tí Dafidi gbọ́ pé àwọn ará Filistia ń gbógun ti àwọn ará Keila, wọ́n sì ń jí ọkà wọn kó ní ibi ìpakà, ó bèèrè lọ́wọ́ OLUWA pé, “Ṣé kí n gbógun ti àwọn ará Filistia?” OLUWA dáhùn pé, “Gbógun tì wọ́n kí o sì gba àwọn ará Keila sílẹ̀.” Àwọn ọkunrin tí ó wà lọ́dọ̀ Dafidi sì sọ fún un pé, “Ní Juda tí a wà níhìn-ín, inú ewu ni a wà, báwo ni yóo ti rí nígbà tí a bá tún lọ gbógun ti àwọn ará Filistia ní Keila?” Dafidi tún bèèrè lọ́wọ́ OLUWA lẹ́ẹ̀kan sí i pé, bóyá kí òun lọ tabi kí òun má lọ. OLUWA sì dáhùn pé, “Lọ sí Keila nítorí n óo fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ará Filistia.” Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ bá lọ gbógun ti àwọn ará Filistia ní Keila, wọ́n pa ọpọlọpọ ninu wọn, wọ́n sì kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ṣe gba àwọn ará Keila sílẹ̀. Nígbà tí Abiatari, ọmọ Ahimeleki sá tọ Dafidi lọ ní Keila, ó mú aṣọ efodu kan lọ́wọ́. Nígbà tí Saulu gbọ́ pé Dafidi wà ní Keila, ó sọ pé, “Ọlọ́run ti fi Dafidi lé mi lọ́wọ́, nítorí ó ti ti ara rẹ̀ mọ́ inú ìlú olódi tí ó ní ìlẹ̀kùn, tí ó sì lágbára.” Saulu bá pe gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ láti gbógun ti Keila kí wọ́n sì ká Dafidi ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ mọ́ ìlú náà. Nígbà tí Dafidi gbọ́ pé Saulu ń gbèrò ibi, ó pe Abiatari alufaa kí ó mú aṣọ efodu wá, láti ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Ọlọrun. Dafidi ní, “OLUWA, Ọlọrun Israẹli, èmi iranṣẹ rẹ gbọ́ pé Saulu ti pinnu láti wá gbógun ti Keila ati láti pa á run nítorí mi. Ǹjẹ́ àwọn alàgbà Keila yóo fà mí lé Saulu lọ́wọ́? Ṣe Saulu yóo wá gẹ́gẹ́ bí mo ti gbọ́? Jọ̀wọ́, OLUWA Ọlọrun Israẹli, fún mi ní èsì.” OLUWA sì dáhùn pé, “Saulu yóo wá.” Dafidi tún bèèrè pé, “Ǹjẹ́ àwọn alàgbà Keila yóo fà mí lé e lọ́wọ́?” OLUWA dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, wọn yóo fà ọ́ lé e lọ́wọ́.” Nítorí náà, Dafidi ati ẹgbẹta (600) àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ kúrò ní Keila lẹsẹkẹsẹ. Nígbà tí Saulu gbọ́ pé Dafidi ti kúrò ní Keila, kò lọ gbógun ti Keila mọ́. Dafidi bá ń lọ gbé orí òkè kan tí ó ṣe é farapamọ́ sí ní aṣálẹ̀ Sifi. Saulu ń wá a lojoojumọ láti pa á, ṣugbọn Ọlọrun kò fi Dafidi lé e lọ́wọ́. Ẹ̀rù ba Dafidi nítorí pé Saulu ń wá ọ̀nà láti pa á. Dafidi ń gbé aṣálẹ̀ Sifi ni Horeṣi. Jonatani ọmọ Saulu wá a lọ sibẹ ó sì fi ọ̀rọ̀ Ọlọrun gbà á níyànjú. Ó sọ fún un pé, “Má bẹ̀rù, nítorí pé ọwọ́ Saulu, baba mi, kò ní tẹ̀ ọ́. O óo jọba lórí Israẹli, n óo sì jẹ́ igbákejì rẹ.” Àwọn mejeeji dá majẹmu níwájú OLUWA; Dafidi dúró ní Horeṣi, Jonatani sì pada sílé. Àwọn ará Sifi kan lọ sọ́dọ̀ Saulu ní Gibea, wọ́n sọ fún un pé, “Dafidi sá pamọ́ sáàrin wa ní Horeṣi ní orí òkè Hakila tí ó wà ní ìhà gúsù Jeṣimoni. Nítorí náà, wá sọ́dọ̀ wa nígbà tí o bá fẹ́, a óo sì fà á lé ọ lọ́wọ́.” Saulu dáhùn pé, “OLUWA yóo bukun yín nítorí pé ẹ káàánú mi. Ẹ lọ nisinsinyii kí ẹ sì tún ṣe ìwádìí dáradára nípa ibi tí ó wà, ati ẹni tí ó rí i níbẹ̀; nítorí mo gbọ́ pé alárèékérekè ẹ̀dá ni Dafidi. Ẹ mọ gbogbo ibi tíí máa ń sá pamọ́ sí dájúdájú, kí ẹ sì wá ròyìn fún mi. N óo ba yín lọ; bí ó bá wà níbẹ̀, n óo wá a kàn, bí ó bá tilẹ̀ wà láàrin ẹgbẹẹgbẹrun eniyan ilẹ̀ Juda.” Wọ́n bá pada sí Sifi ṣáájú Saulu. Ṣugbọn Dafidi ati àwọn ọkunrin rẹ̀ ti wà ní aṣálẹ̀ Maoni tí ó wà ní Araba lápá ìhà gúsù Jeṣimoni. Saulu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ láti wá Dafidi. Ṣugbọn Dafidi gbọ́ nípa rẹ̀, ó sì lọ sá pamọ́ sí ibi òkúta kan tí ó wà ní aṣálẹ̀ Maoni. Nígbà tí Saulu gbọ́, ó lépa Dafidi lọ sí aṣálẹ̀ Maoni. Saulu ati àwọn eniyan rẹ̀ wà ní apá kan òkè náà, Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ sì wà ní apá keji. Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ ń múra láti sá fún Saulu ati àwọn eniyan rẹ̀ nítorí pé wọ́n ń rọ̀gbà yí wọn ká láti mú wọn. Nígbà náà ni oníṣẹ́ kan wá sọ fún Saulu pé, “Pada wá kíákíá, nítorí pé àwọn ará Filistia ti gbógun ti ilẹ̀ wa.” Nítorí náà, Saulu pada lẹ́yìn Dafidi, ó sì lọ bá àwọn ará Filistia jà. Nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni wọ́n ṣe ń pe òkè náà ní Àpáta Àsálà. Láti ibẹ̀, Dafidi lọ farapamọ́ sí Engedi. Nígbà tí Saulu bá àwọn ará Filistia jagun tán, wọ́n sọ fún un pé Dafidi wà ní aṣálẹ̀ Engedi. Saulu mú ẹgbẹẹdogun (3,000) akọni ọmọ ogun lára àwọn ọmọ ogun Israẹli, wọ́n lọ láti wá Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ ní orí àwọn àpáta ewúrẹ́ ìgbẹ́. Nígbà tí Saulu dé ibi tí àwọn agbo aguntan kan wà lẹ́bàá ọ̀nà, ó rí ihò àpáta ńlá kan lẹ́bàá ibẹ̀, ó sì wọ inú rẹ̀ lọ láti sinmi. Ihò náà jẹ́ ibi tí Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ farapamọ́ sí. Àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ Dafidi sọ fún un pé, “Òní gan-an ni ọjọ́ tí OLUWA ti sọ fún ọ nípa rẹ̀, pé òun yóo fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́, kí o lè ṣe é bí ó ti wù ọ́.” Dafidi bá yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ sí ibi tí Saulu wà, ó sì gé etí aṣọ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ọkàn Dafidi bẹ̀rẹ̀ sí dá a lẹ́bi nítorí pé ó gé etí aṣọ Saulu. Ó sọ fún àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Kí OLUWA pa mí mọ́ kúrò ninu ṣíṣe ibi sí oluwa mi, ẹni tí OLUWA ti yàn gẹ́gẹ́ bí ọba. N kò gbọdọ̀ fọwọ́ mi kàn án, nítorí ẹni àmì òróró OLUWA ni.” Nípa báyìí Dafidi dá àwọn eniyan rẹ̀ dúró, kò sì jẹ́ kí wọ́n pa Saulu. Saulu jáde ninu ihò náà, ó bá ọ̀nà rẹ̀ lọ. Dafidi jáde, ó pè é, ó ní, “Olúwa mi ọba,” bí Saulu ti wo ẹ̀yìn ni Dafidi dojúbolẹ̀ láti bọ̀wọ̀ fún un. Ó sọ fún un pé, “Kí ló dé tí o fi ń gbọ́ ti àwọn tí wọ́n ń sọ pé mo fẹ́ pa ọ́? Nisinsinyii, o rí i dájú pé OLUWA fi ọ́ lé mi lọ́wọ́ ninu ihò àpáta. Àwọn kan ninu àwọn ọkunrin mi rọ̀ mí pé kí n pa ọ́, ṣugbọn mo kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Mo sọ fún wọn pé, n kò ní fọwọ́ mi kàn ọ́, nítorí pé ẹni àmì òróró OLUWA ni ọ́. Wò ó! Baba mi, wo etí aṣọ rẹ tí mo mú lọ́wọ́ yìí, ǹ bá pa ọ́ bí mo bá fẹ́, ṣugbọn kàkà bẹ́ẹ̀, mo gé etí aṣọ rẹ. Ó yẹ kí èyí fihàn ọ́ pé n kò ní ìfẹ́ láti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ, tabi láti pa ọ́. Ṣugbọn ìwọ ń lé mi kiri láti pa mí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò ṣe ọ́ níbi. Kí OLUWA dájọ́ láàrin èmi pẹlu rẹ. Kí ó sì jẹ ọ́ níyà fún ìwà burúkú tí ò ń hù sí mi, nítorí pé n kò ní ṣe ọ́ ní ibi kan. Gẹ́gẹ́ bí òwe ìgbà àtijọ́ ti wí, àwọn eniyan burúkú a máa hùwà burúkú, ṣugbọn n kò ní ṣe ọ́ ní ibi kan. Ta ni ìwọ odidi ọba Israẹli ń gbìyànjú láti pa? Ta ni ò ń lépa? Ṣé òkú ajá lásán! Eṣinṣin lásánlàsàn! Kí OLUWA dájọ́ láàrin èmi pẹlu rẹ, kí ó gba ọ̀rọ̀ náà yẹ̀wò, kí ó gbèjà mi, kí ó sì gbà mí, lọ́wọ́ rẹ.” Nígbà tí Dafidi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, Saulu dáhùn pé, “Ṣé ohùn rẹ ni mò ń gbọ́, Dafidi ọmọ mi?” Saulu sì bẹ̀rẹ̀ sí sọkún. Ó wí fún Dafidi pé, “Eniyan rere ni ọ́, èmi ni eniyan burúkú, nítorí pé oore ni ò ń ṣe mí, ṣugbọn èmi ń ṣe ọ́ ní ibi. Lónìí, o ti fi bí o ti jẹ́ eniyan rere sí mi tó hàn mí, nítorí pé o kò pa mí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA fi mí lé ọ lọ́wọ́. Ǹjẹ́ bí eniyan bá rí ọ̀tá rẹ̀, ó lè jẹ́ kí ó lọ ní alaafia? Kí OLUWA bukun ọ nítorí ohun tí o ṣe fún mi lónìí. Nisinsinyii, mo mọ̀ dájú pé o óo jọba ilẹ̀ Israẹli, ìjọba Israẹli yóo sì tẹ̀síwájú nígbà tìrẹ. Nítorí náà, búra fún mi pé o kò ní pa ìdílé mi run lẹ́yìn mi, ati pé o kò ní pa orúkọ mi rẹ́ ní ìdílé baba mi.” Dafidi bá búra fún Saulu. Saulu ati àwọn eniyan rẹ̀ pada sílé, Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ sì pada sí ibi tí wọ́n sá pamọ́ sí. Nígbà tí Samuẹli kú, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli kó ara wọn jọ láti ṣọ̀fọ̀ rẹ̀. Wọ́n sì sin òkú rẹ̀ sí ilé rẹ̀ ní Rama. Lẹ́yìn náà, Dafidi lọ sí aṣálẹ̀ Parani. Ọkunrin kan wà ní ìlú Maoni tí ń ṣe òwò ní Kamẹli. Ọkunrin náà ní ọrọ̀ lọpọlọpọ; ó ní ẹgbẹẹdogun aguntan (3,000) ati ẹgbẹrun (1,000) ewúrẹ́, Kamẹli níí ti máa ń gé irun aguntan rẹ̀. Orúkọ ọkunrin náà ni Nabali, iyawo rẹ̀ sì ń jẹ́ Abigaili. Obinrin náà jẹ́ ọlọ́gbọ́n ati arẹwà, ṣugbọn ọkọ rẹ̀ jẹ́ òǹrorò ati eniyan burúkú. Ìdílé Kalebu ni ìdílé rẹ̀. Dafidi gbọ́ ninu aṣálẹ̀ pé Nabali ń gé irun aguntan rẹ̀, ó bá rán ọdọmọkunrin mẹ́wàá lọ sí Kamẹli láti lọ rí Nabali, kí wọ́n sì kí i ní orúkọ òun. Ó ní kí wọ́n kí i báyìí pé, “Alaafia fún ọ, ati fún ilé rẹ ati fún gbogbo ohun tí o ní. Mo gbọ́ pé ò ń gé irun àwọn aguntan rẹ, mo sì fẹ́ kí o mọ̀ pé àwọn olùṣọ́ aguntan rẹ wà lọ́dọ̀ wa fún ìgbà pípẹ́, n kò sì ṣe wọ́n ní ibi kankan. Kò sí ohun tí ó jẹ́ tiwọn tí ó sọnù ní gbogbo ìgbà tí wọ́n wà ní Kamẹli. Bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọdọmọkunrin rẹ, wọn yóo sì sọ fún ọ. Ọjọ́ ọdún ni ọjọ́ òní, nítorí náà jẹ́ kí àwọn ọmọkunrin yìí rí ojurere lọ́dọ̀ rẹ. Jọ̀wọ́ mú ohunkohun tí ó bá wà ní àrọ́wọ́tó rẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ, ati fún èmi Dafidi, ọmọ rẹ.” Nígbà tí àwọn tí Dafidi rán dé ibẹ̀, wọ́n jíṣẹ́ fún Nabali, ní orúkọ Dafidi, wọ́n sì dúró. Nabali dá àwọn iranṣẹ náà lóhùn pé, “Ta ni Dafidi? Ta ni ọmọ Jese? Ọpọlọpọ iranṣẹ ni ó wà nisinsinyii tí wọn ń sá kúrò ní ọ̀dọ̀ oluwa wọn. Ṣé kí n wá mú oúnjẹ mi ati omi mi ati ẹran tí mo pa fún àwọn tí wọn ń gé irun aguntan mi, kí n sì gbé e fún àwọn tí n kò mọ ibi tí wọ́n ti wá?” Àwọn ọdọmọkunrin náà bá pada lọ sọ gbogbo ohun tí Nabali sọ fún wọn fún Dafidi. Dafidi sì pàṣẹ fún àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ẹ sán idà yín mọ́ ìdí.” Gbogbo wọn sì ṣe bí ó ti wí; òun pàápàá sì sán idà tirẹ̀ náà mọ́ ìdí. Irinwo ninu àwọn ọdọmọkunrin rẹ̀ bá a lọ; igba (200) sì dúró ti ẹrù wọn. Ọ̀kan ninu àwọn ọdọmọkunrin Nabali sọ fún Abigaili, iyawo Nabali pé, “Dafidi rán àwọn iranṣẹ láti aṣálẹ̀ wá sọ́dọ̀ oluwa wa, ṣugbọn ó kanra mọ́ wọn. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ọkunrin náà tọ́jú wa, wọn kò sì ṣe ibi kankan sí wa, nǹkankan tí ó jẹ́ tiwa kò sì sọnù nígbà tí a wà pẹlu wọn ní oko. Wọ́n dáàbò bò wá tọ̀sán tòru, ní gbogbo ìgbà tí a wà lọ́dọ̀ wọn, tí à ń tọ́jú agbo ẹran wa. Jọ̀wọ́ ro ọ̀rọ̀ náà dáradára, kí o sì pinnu ohun tí o bá fẹ́ ṣe; nítorí pé wọ́n ti gbèrò ibi sí oluwa wa ati ìdílé rẹ̀, ọlọ́kàn líle sì ni oluwa wa, ẹnikẹ́ni kò lè bá a sọ̀rọ̀.” Abigaili bá yára mú igba (200) burẹdi ati ìgò ọtí waini meji ati aguntan marun-un tí wọ́n ti sè ati òṣùnwọ̀n ọkà yíyan marun-un ati ọgọrun-un ìdì àjàrà gbígbẹ ati igba (200) àkàrà tí wọ́n fi èso ọ̀pọ̀tọ́ dín, ó sì dì wọ́n ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Ó sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ẹ máa lọ ṣiwaju, èmi náà ń bọ̀ lẹ́yìn,” ṣugbọn kò sọ fún ọkọ rẹ̀. Bí ó ti ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ lọ, tí ó dé abẹ́ òkè kan, ó rí i tí Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ ń bọ̀ níwájú. Dafidi ti wí pé, “Ṣé lásán ni mo dáàbò bo agbo ẹran Nabali ninu aṣálẹ̀, tí kò sí ohun ìní rẹ̀ kan tí ó sọnù. Ṣé bí ó ti yẹ kí ó fi ibi san ire fún mi nìyí. Kí Ọlọrun pa mí bí mo bá fi ẹnikẹ́ni sílẹ̀ láìpa ninu àwọn eniyan Nabali títí di òwúrọ̀ ọ̀la.” Nígbà tí Abigaili rí Dafidi, ó sọ̀kalẹ̀ kíákíá, ó wólẹ̀, ó sì dojúbolẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ Dafidi, ó bẹ̀ ẹ́ pé, “Jọ̀wọ́ oluwa mi, gbọ́ ti èmi iranṣẹbinrin rẹ, kí o sì jẹ́ kí n ru ẹ̀bi àṣìṣe Nabali. Jọ̀wọ́ má ṣe ka aláìmòye yìí sí, nítorí Nabali ni orúkọ rẹ̀, bí orúkọ rẹ̀ tí ń jẹ́, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìwà rẹ̀ rí. Oluwa mi, n kò rí àwọn iranṣẹ rẹ nígbà tí wọ́n wá. OLUWA tìkararẹ̀ ni ó ti ká ọ lọ́wọ́ kò láti má ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ati láti má gbẹ̀san. Nisinsinyii, oluwa mi, níwọ̀n ìgbà tí OLUWA wà láàyè, gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ ati àwọn tí wọn ń ro ibi sí ọ yóo dàbí Nabali. Jọ̀wọ́ gba ẹ̀bùn tí èmi iranṣẹbinrin rẹ mú wá fún ọ kí o sì fi fún àwọn ọkunrin tí wọ́n tẹ̀lé ọ. Jọ̀wọ́ dáríjì mí fún gbogbo àìṣedéédé mi. Dájúdájú OLUWA yóo jẹ́ kí o jọba ati àwọn ọmọ rẹ pẹlu. Nítorí pé ogun OLUWA ni ò ń jà, o kò sì hùwà ibi kan ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. Bí ẹnikẹ́ni bá sì ń gbèrò láti ṣe ọ́ ní ibi tabi láti pa ọ́, OLUWA yóo dáàbò bò ọ́ bí eniyan ti ń dáàbò bo ohun ìní olówó iyebíye. Ṣugbọn àwọn ọ̀tá rẹ ni a óo parun. Nígbà tí OLUWA bá mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ tí ó sì fi ọ́ jọba ní Israẹli, o kò ní ní ìbànújẹ́ ọkàn pé o ti paniyan rí láìnídìí tabi pé o ti gbẹ̀san ara rẹ. Nígbà tí OLUWA bá sì bukun ọ, jọ̀wọ́ má ṣe gbàgbé èmi iranṣẹbinrin rẹ.” Dafidi dáhùn pé, “Ògo ni fún OLUWA Ọlọrun Israẹli tí ó rán ọ sí mi lónìí. Ibukun ni fún ọ, fún ọgbọ́n tí o lò ati ohun tí o ṣe lónìí, tí o fà mí sẹ́yìn kúrò ninu ìpànìyàn ati ìgbẹ̀san. OLUWA ti dá mi dúró láti má ṣe ọ́ ní ibi. Ṣugbọn mo fi OLUWA ṣe ẹlẹ́rìí mi, bí o kò bá yára láti pàdé mi ni, gbogbo àwọn ọkunrin ilé Nabali ni ìbá kú kí ilẹ̀ ọ̀la tó mọ́.” Dafidi gba ẹ̀bùn tí ó mú wá, ó sì sọ fún un pé, “Máa lọ sílé ní alaafia, kí o má sì ṣe bẹ̀rù, n óo ṣe ohun tí o sọ.” Nígbà tí Abigaili pada dé ilé ó bá Nabali ninu àsè bí ọba. Inú rẹ̀ dùn nítorí pé ó ti mu ọtí ní àmupara. Abigaili kò sì sọ nǹkankan fún un títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji. Nígbà tí ojú rẹ̀ wálẹ̀ tán; Abigaili sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún un. Ní ọjọ́ kẹwaa lẹ́yìn náà, OLUWA pa Nabali. Nígbà tí Dafidi gbọ́ pé Nabali ti kú, ó ní, “Ìyìn ni fún OLUWA tí ó gbẹ̀san lára Nabali nítorí àfojúdi tí ó ṣe sí mi. Ìyìn ni fún OLUWA tí ó sì fa èmi iranṣẹ rẹ̀ sẹ́yìn kúrò ninu ṣíṣe ibi. OLUWA ti jẹ Nabali níyà fún ìwà burúkú rẹ̀.” Dafidi bá ranṣẹ sí Abigaili pé òun fẹ́ fẹ́ ẹ. Àwọn iranṣẹ Dafidi lọ sọ́dọ̀ Abigaili ní Kamẹli, wọ́n ní, “Dafidi ní kí á mú ọ wá, kí o lè jẹ́ aya òun.” Abigaili bá wólẹ̀ ó ní, “Iranṣẹ Dafidi ni mí, mo sì ti ṣetán láti ṣan ẹsẹ̀ àwọn iranṣẹ rẹ̀.” Ó yára gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, òun pẹlu àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ marun-un, wọ́n sì tẹ̀lé àwọn iranṣẹ Dafidi lọ, Abigaili sì di aya Dafidi. Dafidi ti fẹ́ Ahinoamu ará Jesireeli, ó sì tún fẹ́ Abigaili pẹlu. Ṣugbọn Saulu ti mú Mikali, ọmọ rẹ̀ tí ó jẹ́ iyawo Dafidi, ó ti fún Paliti ọmọ Laiṣi tí ó wá láti Galimu pé kí ó fi ṣe aya. Àwọn ọkunrin kan, ará Sifi lọ sọ fún Saulu ní Gibea pé, “Dafidi farapamọ́ sí òkè Hakila tí ó wà ní apá ìlà oòrùn Jeṣimoni.” Lẹsẹkẹsẹ, Saulu mú ẹgbẹẹdogun (3,000) akọni ninu àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n lọ wá Dafidi ninu aṣálẹ̀ Sifi. Wọ́n pabùdó wọn sí ẹ̀bá ọ̀nà ní òkè Hakila, Dafidi sì wà ninu aṣálẹ̀ náà. Nígbà tí Dafidi mọ̀ pé Saulu ń wá òun kiri, ó rán amí láti rí i dájú pé Saulu wà níbẹ̀. Dafidi lọ lẹsẹkẹsẹ láti rí ibi tí Saulu ati Abineri, ọmọ Neri, olórí ogun Saulu, dùbúlẹ̀ sí. Saulu wà ninu àgọ́, àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì pàgọ́ yí i ká. Dafidi bá bèèrè lọ́wọ́ Ahimeleki, ará Hiti ati Abiṣai ọmọ Seruaya, arakunrin Joabu pé, “Ta ni yóo bá mi lọ sí ibùdó Saulu?” Abiṣai dáhùn pé, “N óo bá ọ lọ.” Dafidi ati Abiṣai bá lọ sí ibùdó Saulu ní òru ọjọ́ náà, Saulu sì ń sùn ní ààrin àgọ́, ó fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ gúnlẹ̀ lẹ́bàá ìrọ̀rí rẹ̀. Abineri ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì sùn yí i ká. Abiṣai bá sọ fún Dafidi pé, “Ọlọrun ti fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́ ní òní yìí, gbà mí láàyè kí n yọ ọ̀kọ̀, kí n sì gún un ní àgúnpa lẹ́ẹ̀kanṣoṣo.” Ṣugbọn Dafidi sọ fún Abiṣai pé, “O kò gbọdọ̀ ṣe é ní ibi kan, nítorí ẹni tí ó bá pa ẹni àmì òróró OLUWA yóo jẹ̀bi. Níwọ̀n ìgbà tí OLUWA wà láàyè, OLUWA yóo pa á; tabi kí ọjọ́ ikú rẹ̀ pé, tabi kí ó kú lójú ogun. Kí OLUWA má ṣe jẹ́ kí n pa ẹni àmì òróró rẹ̀. Nítorí náà, jẹ́ kí á mú ọ̀kọ̀ rẹ̀ ati ìgò omi rẹ̀ kí á sì máa lọ.” Dafidi bá mú ọ̀kọ̀ ati ìgò omi Saulu ní ìgbèrí rẹ̀, òun pẹlu Abiṣai sì jáde lọ. Kò sí ẹnikẹ́ni ninu Saulu ati àwọn eniyan rẹ̀ tí ó mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, tabi tí ó jí nítorí OLUWA kùn wọ́n ní oorun. Dafidi kọjá sí òdìkejì àfonífojì ní orí òkè níbi tí ó jìnnà díẹ̀. Ó sì ké sí àwọn ọmọ ogun Saulu ati Abineri pé, “Abineri! Ǹjẹ́ ò ń gbọ́ ohùn mi bí!” Abineri sì dáhùn pé, “Ìwọ ta ni ń pariwo! Tí o fẹ́ jí ọba?” Dafidi dáhùn pé, “Ǹjẹ́ ìwọ kọ́ ni alágbára jùlọ ní Israẹli? Kí ló dé tí o kò dáàbò bo ọba, oluwa rẹ? Láìpẹ́ yìí ni ẹnìkan wọ inú àgọ́ yín láti pa oluwa rẹ. Ohun tí o ṣe yìí kò dára, mo fi OLUWA ṣe ẹ̀rí pé, ó yẹ kí o kú, nítorí pé o kò dáàbò bo oluwa rẹ, ẹni àmì òróró OLUWA. Níbo ni ọ̀kọ̀ ọba wà? Ibo sì ni ìgò omi tí ó wà ní ìgbèrí rẹ̀ wà pẹlu?” Saulu mọ̀ pé Dafidi ni ó ń sọ̀rọ̀, ó bá bèèrè pé, “Dafidi ọmọ mi, ṣé ìwọ ni ò ń sọ̀rọ̀?” Dafidi dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, oluwa mi. Kí ló dé tí o fi ń lépa èmi iranṣẹ rẹ? Kí ni mo ṣe? Kí sì ni ẹ̀ṣẹ̀ mi? Oluwa mi, gbọ́ ohun tí èmi iranṣẹ rẹ fẹ́ sọ. Bí ó bá jẹ́ pé OLUWA ni ó gbé ọ dìde sí mi, kí ó gba ẹbọ ẹ̀bẹ̀, ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé eniyan ni, kí ègún OLUWA wá sórí olúwarẹ̀, nítorí wọ́n lé mi jáde, kí n má baà ní ìpín ninu ilẹ̀ ìní tí OLUWA fún àwọn eniyan rẹ̀. Wọ́n ń sọ fún mi pé kí n lọ máa bọ oriṣa. Má jẹ́ kí n kú sílẹ̀ àjèjì níbi tí OLUWA kò sí. Kí ló dé tí ọba Israẹli fi ń lépa èmi kékeré yìí, bí ẹni ń dọdẹ àparò lórí òkè?” Saulu dáhùn pé, “Mo ti ṣe ibi, máa bọ̀ Dafidi, ọmọ mi. N kò ní ṣe ọ́ ní ibi mọ́, nítorí pé ẹ̀mí mi níye lórí lójú rẹ lónìí. Mo ti hùwà òmùgọ̀, ohun tí mo ṣe burú pupọ.” Dafidi dáhùn pé, “Ọ̀kọ̀ rẹ nìyí, oluwa mi, jẹ́ kí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun rẹ wá gbà á. OLUWA a máa san ẹ̀san rere fún àwọn tí wọ́n bá jẹ́ olóòótọ́ ati olódodo. Lónìí, OLUWA fi ọ́ lé mi lọ́wọ́, ṣugbọn mo kọ̀ láti ṣe ọ́ ní ibi, nítorí pé ẹni àmì òróró OLUWA ni ọ́. Gẹ́gẹ́ bí mo ti dá ẹ̀mí rẹ sí lónìí, kí OLUWA ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi, kí ó sì yọ mí kúrò ninu gbogbo ìṣòro.” Saulu dáhùn pé, “Ọlọ́run yóo bukun ọ, ọmọ mi, o óo máa ṣe àṣeyọrí ninu gbogbo ohun tí o bá ń ṣe.” Dafidi bá bá tirẹ̀ lọ, Saulu sì pada sí ilé rẹ̀. Dafidi rò ní ọkàn rẹ̀ pé Saulu yóo pa òun ní ọjọ́ kan, nítorí náà ohun tí ó dára jù ni kí òun sá àsálà lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Filistia. Ó ní Saulu yóo dẹ́kun láti máa wá òun kiri ní ilẹ̀ Israẹli, òun óo sì fi bẹ́ẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Dafidi ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹta (600), bá lọ sọ́dọ̀ Akiṣi, ọmọ Maoki, ọba Gati. Wọ́n ń gbé Gati pẹlu àwọn ará ilé wọn. Àwọn aya Dafidi mejeeji, Ahinoamu ará Jesireeli ati Abigaili ará Kamẹli, opó Nabali, sì wà pẹlu rẹ̀ níbẹ̀. Nígbà tí Saulu gbọ́ pé Dafidi ti sá àsálà lọ sí Gati, ó dẹ́kun láti máa wá a kiri. Dafidi sì sọ fún Akiṣi pé, “Bí mo bá rí ojurere rẹ, jọ̀wọ́ fún mi ní ààyè ní ọ̀kan ninu àwọn ìletò agbègbè yìí kí n máa gbé. Kí ló dé tí èmi iranṣẹ rẹ yóo máa gbé inú ìlú kan náà pẹlu rẹ?” Akiṣi fún un ní ìlú Sikilagi, nítorí náà ni Sikilagi fi jẹ́ ti àwọn ọba Juda títí di òní yìí. Dafidi gbé ní ilẹ̀ àwọn ará Filistia fún ọdún kan ati oṣù mẹrin. Ní àkókò náà, Dafidi ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti àwọn ará Geṣuri, ati àwọn ará Girisi ati àwọn Amaleki, tí wọ́n ti ń gbé ibẹ̀ fún ìgbà pípẹ́, títí dé Ṣuri ati ilẹ̀ Ijipti. Dafidi pa gbogbo wọn, lọkunrin ati lobinrin, ó sì kó àwọn aguntan, mààlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati ràkúnmí wọn, ati aṣọ wọn, ó sì pada lọ bá Akiṣi. Bí Akiṣi bá bèèrè pé, “Àwọn wo ni ẹ kógun lọ bá lónìí?” Dafidi á sì dáhùn pé, “Ìhà gúsù Juda ni, tabi kí ó sọ wí pé ìhà gúsù Jerameeli tabi ìhà gúsù Keni.” Dafidi kò dá ẹnìkankan sí yálà ọkunrin tabi obinrin kí wọ́n má baà mú ìròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lọ sí Gati, bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ń ṣe ní gbogbo ìgbà tí ó ń gbé ààrin àwọn ará Filistia. Ṣugbọn Akiṣi gba Dafidi gbọ́, ó sì wí ninu ara rẹ̀ pé, “Àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ̀, kórìíra rẹ̀ lọpọlọpọ, nítorí náà yóo jẹ́ iranṣẹ mi laelae.” Nígbà tí ó ṣe, àwọn ará Filistia kó ara wọn jọ láti bá Israẹli jagun. Akiṣi sọ fún Dafidi pé, “Ìwọ ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ yóo jà fún mi.” Dafidi dáhùn pé, “Ó dára, o óo sì rí ohun tí èmi iranṣẹ rẹ lè ṣe.” Akiṣi bá ní, òun óo fi Dafidi ṣe olùṣọ́ òun títí lae. Samuẹli ti kú, àwọn Israẹli ti ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ti sin ín sí Rama ìlú rẹ̀. Saulu ti lé gbogbo àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ati àwọn oṣó kúrò ní ilẹ̀ Israẹli. Àwọn ará Filistia sì kó ara wọn jọ, wọ́n pa ibùdó sí Ṣunemu. Saulu náà kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ, wọ́n pa ibùdó sí Giliboa. Nígbà tí Saulu rí àwọn ọmọ ogun Filistini, àyà rẹ̀ já, ẹ̀rù sì bà á lọpọlọpọ. Nígbà tí Saulu bèèrè lọ́wọ́ OLUWA ohun tí yóo ṣe, OLUWA kò dá a lóhùn yálà nípa àlá tabi nípa Urimu tabi nípasẹ̀ àwọn wolii. Saulu bá sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ẹ bá mi wá obinrin kan tí ó bá jẹ́ abókùúsọ̀rọ̀, kí n lè lọ ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ rẹ̀.” Wọn sì sọ fún un pé, “Obinrin kan wà ní Endori tí ó jẹ́ abókùúsọ̀rọ̀.” Saulu pa ara dà, ó wọ aṣọ mìíràn, òun pẹlu àwọn ọkunrin meji kan lọ sọ́dọ̀ obinrin náà ní òru, Saulu sì sọ fún obinrin náà pé, “Lo ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀ rẹ láti pe ẹni tí mo bá sọ fún ọ wá.” Obinrin náà dáhùn pé, “Kí ló dé tí o fi ń dẹ tàkúté fún mi láti pa mí? O ṣá mọ ohun tí Saulu ọba ṣe, tí ó lé gbogbo àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ati àwọn oṣó kúrò ní Israẹli.” Saulu bá búra ní orúkọ OLUWA pé, “Bí OLUWA ti ń bẹ, ibi kan kò ní ṣẹlẹ̀ sí ọ nítorí èyí.” Obinrin náà dáhùn pé, “Ta ni kí n pè fún ọ?” Saulu dáhùn pe, “Pe Samuẹli fún mi.” Nígbà tí obinrin náà rí Samuẹli, ó kígbe lóhùn rara pé, “Kí ló dé tí o fi tàn mí? Àṣé Saulu ọba ni ọ́.” Saulu bá sọ fún un pé, “Má bẹ̀rù, sọ ohun tí o rí fún mi.” Obinrin náà dáhùn pé, “Mo rí ẹbọra kan, tí ń jáde bọ̀ láti inú ilẹ̀.” Saulu bèèrè pé, “Báwo ló rí?” Obinrin náà dáhùn pé, “Ọkunrin arúgbó kan ló ń bọ̀, ó sì fi aṣọ bora.” Saulu mọ̀ pé Samuẹli ni, ó sì tẹríba. Samuẹli bi Saulu pé, “Kí ló dé tí o fi ń yọ mí lẹ́nu? Kí ló dé tí o fi gbé mi dìde?” Saulu dáhùn pé, “Mo wà ninu ìpọ́njú ńlá nítorí pé àwọn ará Filistia ń bá mi jagun, Ọlọrun sì ti kọ̀ mí sílẹ̀, nítorí pé kò fún mi ní ìtọ́sọ́nà, yálà láti ẹnu wolii kan ni, tabi lójú àlá. Nítorí náà ni mo ṣe pè ọ́, pé kí o lè sọ ohun tí n óo ṣe fún mi.” Samuẹli dáhùn pé, “Kí ló dé tí o fi ń bi mí, nígbà tí OLUWA ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, tí ó sì ti di ọ̀tá rẹ? OLUWA ti ṣe sí ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí ó sọ láti ẹnu mi. Ó ti gba ìjọba náà kúrò lọ́wọ́ rẹ, ó sì ti fún Dafidi, aládùúgbò rẹ. O ṣàìgbọràn sí àṣẹ OLUWA, nítorí pé, o kò pa gbogbo àwọn ará Amaleki ati àwọn nǹkan ìní wọn run. Ìdí nìyí tí OLUWA fi ṣe àwọn nǹkan wọnyi sí ọ lónìí. OLUWA yóo fa ìwọ ati Israẹli lé àwọn ará Filistia lọ́wọ́. Ní ọ̀la ni ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ yóo kú; OLUWA yóo sì fa àwọn ọmọ ogun Israẹli lé àwọn ará Filistia lọ́wọ́.” Lẹ́sẹ̀kan náà, Saulu ṣubú lulẹ̀ gbalaja, nítorí pé ohun ti Samuẹli sọ dẹ́rùbà á gidigidi, àárẹ̀ sì mú un nítorí pé, kò jẹun ní gbogbo ọ̀sán ati òru náà. Nígbà tí obinrin náà rí i pé ó wà ninu ọpọlọpọ ìbànújẹ́, ó sọ fún un pé, “Oluwa mi, mo fi ẹ̀mí mi wéwu láti ṣe ohun tí o bèèrè. Ǹjẹ́, nisinsinyii, jọ̀wọ́ ṣe ohun tí mò ń tọrọ lọ́wọ́ rẹ fún mi. Jẹ́ kí n tọ́jú oúnjẹ fún ọ, kí o jẹ ẹ́, kí o lè lókun nígbà tí o bá ń lọ.” Saulu kọ̀, kò fẹ́ jẹun. Ṣugbon àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati obinrin náà bẹ̀ ẹ́ kí ó jẹun. Ó gbà, ó dìde nílẹ̀, ó sì jókòó lórí ibùsùn. Obinrin náà yára pa ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù tí ó ń sìn, ó sì ṣe burẹdi díẹ̀ láì fi ìwúkàrà sí i. Ó gbé e kalẹ̀ níwájú wọn; Saulu ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ jẹ ẹ́, wọ́n sì jáde lọ ní òru náà. Àwọn ará Filistia kó gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn jọ sí Afeki, àwọn ọmọ ogun Israẹli sì pa ibùdó sí etí orísun omi tí ó wà ní àfonífojì Jesireeli. Bí àwọn ọba Filistini ti ń kọjá pẹlu àwọn ọmọ ogun wọn ní ọgọọgọrun-un ati ẹgbẹẹgbẹrun, Dafidi ati àwọn ọkunrin rẹ̀ tò sẹ́yìn ọba Akiṣi. Àwọn olórí ogun Filistini bèèrè pé, “Kí ni àwọn Heberu wọnyi ń ṣe níbí?” Akiṣi sì dá wọn lóhùn pé, “Ṣebí Dafidi, iranṣẹ Saulu ọba Israẹli nìyí, ó ti wà lọ́dọ̀ mi láti ìgbà pípẹ́, n kò tíì rí àṣìṣe kan lọ́wọ́ rẹ̀ láti ìgbà tí ó ti dé ọ̀dọ̀ mi títí di òní yìí.” Àwọn olórí ogun náà bínú sí i gidigidi, wọ́n ní, “Sọ fún un, kí ó pada síbi tí o fún un, kí ó má bá wa lọ sójú ogun, kí ó má baà dojú ìjà kọ wá. Kí ni ìwọ rò pé yóo fẹ́ fi bá oluwa rẹ̀ làjà? Ṣebí nípa pípa àwọn ọmọ ogun wa ni. Àbí nítorí Dafidi yìí kọ́ ni àwọn ọmọbinrin Israẹli ṣe ń jó tí wọ́n sì ń kọrin pé, ‘Saulu pa ẹgbẹẹgbẹrun tirẹ̀, ṣugbọn Dafidi pa ẹgbẹẹgbaarun tirẹ̀?’ ” Akiṣi pe Dafidi, ó sọ fún un pé, “Mo fi OLUWA ṣe ẹlẹ́rìí pé o jẹ́ olóòótọ́ sí mi, inú mi sì dùn sí i pé kí o bá mi lọ sójú ogun yìí, nítorí pé n kò tíì rí ẹ̀bi kan lọ́wọ́ rẹ láti ìgbà tí o ti dé ọ̀dọ̀ mi títí di òní. Ṣugbọn àwọn olórí ogun kò gbà pé kí o bá wa lọ. Nítorí náà, jọ̀wọ́ pada ní alaafia, kí o má baà múnú bí wọn.” Dafidi dáhùn pé, “Kí ni mo ṣe? Kí ni ìdí rẹ̀ tí n kò fi ní lè lọ bá àwọn ọ̀tá rẹ jà, nígbà tí o kò rí ẹ̀bi kan lọ́wọ́ mi láti ìgbà tí mo ti dé ọ̀dọ̀ rẹ?” Akiṣi sì dáhùn pé, “Nítòótọ́ ni, mo mọ̀ pé o jẹ́ ẹni rere bí angẹli OLUWA, ṣugbọn àwọn olórí ogun ti sọ pé, o kò lè bá wa lọ sójú ogun. Nítorí náà, dìde ní òwúrọ̀, ìwọ ati àwọn iranṣẹ oluwa rẹ, tí wọ́n bá ọ wá, kí ẹ sì máa lọ ní kété tí ilẹ̀ bá ti mọ́.” Dafidi ati àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bá dìde, wọ́n lọ sí ilẹ̀ Filistini, àwọn ọmọ ogun Filistini sì lọ sí Jesireeli. Nígbà tí Dafidi ati àwọn ọkunrin rẹ̀ pada dé Sikilagi ní ọjọ́ kẹta, wọ́n rí i pé àwọn ará Amaleki ti gbógun ti Nẹgẹbu ati Sikilagi, wọ́n ṣẹgun Sikilagi, wọ́n sì sun ìlú náà níná; wọ́n kó gbogbo obinrin ati àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ lẹ́rú, àtọmọdé, àtàgbà, wọn kò sì pa ẹnikẹ́ni. Nígbà tí Dafidi ati àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ dé, wọ́n rí i pé wọ́n ti dáná sun ìlú náà, wọ́n sì ti kó àwọn aya wọn ati àwọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin lẹ́rú. Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ sọkún títí tí ó fi rẹ̀ wọ́n. Wọ́n kó àwọn aya Dafidi mejeeji, Ahinoamu ará Jesireeli ati Abigaili opó Nabali lẹ́rú pẹlu. Dafidi sì wà ninu ìbànújẹ́, nítorí pé inú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bàjẹ́ nítorí àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì ń gbèrò láti sọ ọ́ ní òkúta pa. Ṣugbọn Dafidi túbọ̀ ní igbẹkẹle ninu OLUWA Ọlọrun rẹ̀. Dafidi sọ fún Abiatari alufaa, ọmọ Ahimeleki, pé kí ó mú efodu wá. Abiatari sì mú un wá. Dafidi bá bèèrè lọ́wọ́ OLUWA pé, “Ṣé kí n lépa àwọn ọmọ ogun náà? Ṣé n óo bá wọn?” OLUWA sì dáhùn pé, “Lépa wọn, o óo bá wọn, o óo sì gba àwọn eniyan rẹ.” Dafidi ati àwọn ẹgbẹta (600) ọmọlẹ́yìn rẹ̀, bá lọ, nígbà tí wọ́n dé odò Besori, apá kan ninu wọn dúró ní etí odò náà. Dafidi ati irinwo (400) eniyan sì ń lépa wọn lọ, ṣugbọn àwọn igba (200) eniyan tí àárẹ̀ mú kò lè la odò náà kọjá, wọ́n sì dúró sí etí odò. Àwọn ọmọlẹ́yìn Dafidi rí ọmọkunrin ará Ijipti kan ninu oko, wọ́n sì mú un wá sọ́dọ̀ Dafidi, wọ́n fún un ní oúnjẹ ati omi, èso ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ ati ìdì àjàrà meji. Nígbà tí ó jẹun tán, ó ní agbára nítorí pé kò tíì jẹun, kò sì mu omi fún ọjọ́ mẹta sẹ́yìn. Dafidi bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ta ni oluwa rẹ, níbo ni o sì ti wá?” Ó dáhùn pé, “Ará Ijipti ni mí, ẹrú ará Amaleki kan. Ọjọ́ kẹta nìyí tí oluwa mi ti fi mí sílẹ̀ níhìn-ín, nítorí pé ara mi kò dá. A ti jagun ní Nẹgẹbu ní agbègbè Kereti ati ní agbègbè Juda ati ní agbègbè Nẹgẹbu ti Kalebu, a sì sun Sikilagi níná.” Dafidi bi í léèrè pé, “Ṣé o lè mú mi lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ogun náà?” Ó dáhùn pé, “N óo mú ọ lọ, bí o bá ṣèlérí ní orúkọ Ọlọrun pé o kò ní pa mí, tabi kí o fi mí lé oluwa mi lọ́wọ́.” Ó mú Dafidi lọ bá wọn. Àwọn ọmọ ogun náà fọ́n káàkiri, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì ń jó, nítorí ọpọlọpọ ìkógun tí wọ́n rí kó ní ilẹ̀ àwọn ará Filistia ati Juda. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, Dafidi kọlù wọ́n, ó sì pa wọ́n títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà. Kò sì sí ẹni tí ó là ninu wọn, àfi irinwo ọdọmọkunrin tí wọ́n gun ràkúnmí sá lọ. Dafidi sì gba àwọn eniyan rẹ̀ pada, ati gbogbo nǹkan tí àwọn ará Amaleki náà kó, ati àwọn iyawo rẹ̀ mejeeji. Kò sí ohun kan tí ó nù, Dafidi gba gbogbo àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin rẹ̀ pada, ati gbogbo nǹkan tí àwọn ará Amaleki kó. Ó gba gbogbo àwọn ẹran ọ̀sìn pẹlu. Àwọn eniyan náà sì ń dá àwọn ẹran ọ̀sìn náà jọ níwájú Dafidi, wọ́n ń sọ pé, “Ìkógun Dafidi nìyí.” Dafidi lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn igba (200) eniyan tí àárẹ̀ mú pupọ, tí wọn kò lè kọjá odò, ṣugbọn tí wọ́n dúró lẹ́yìn odò Besori; àwọn náà wá pàdé Dafidi ati àwọn tí wọ́n bá a lọ. Dafidi sì kí wọn dáradára. Àwọn tí wọ́n jẹ́ eniyan burúkú ati òǹrorò láàrin àwọn tí wọ́n bá Dafidi lọ ní, “Nítorí pé wọn kò bá wa lọ, a kò ní fún wọn ninu ìkógun wa tí a gbà pada, àfi aya ati àwọn ọmọ wọn nìkan ni wọ́n lè gbà.” Ṣugbọn Dafidi dáhùn pé, “Ẹ̀yin arakunrin mi, ẹ ẹ̀ gbọdọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí gbogbo ohun tí OLUWA fifún wa. Òun ni ó pa wá mọ́ tí ó sì fún wa ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọmọ ogun tí wọ́n dojú ìjà kọ wá. Kò sí ẹni tí yóo fara mọ́ àbá yín yìí. Gbogbo wa ni a óo jọ pín ìkógun náà dọ́gba-dọ́gba, ati àwọn tí ó lọ ati àwọn tí ó dúró ti ẹrù.” Láti ọjọ́ náà ni ó ti sọ ọ́ di òfin ati ìlànà ní Israẹli, títí di òní olónìí. Nígbà tí Dafidi pada dé Sikilagi, ó fi ẹ̀bùn ranṣẹ sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olórí Juda; ó mú ninu ìkógun náà, ó ní, “Ẹ̀bùn yín nìyí lára ìkógun tí a kó láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀tá OLUWA.” Ó fi ranṣẹ sí àwọn tí wọ́n wà ní Bẹtẹli, ati àwọn tí wọ́n wà ní Ramoti ti Nẹgẹbu, ati Jatiri; ati àwọn tí wọ́n wà ní Aroeri, Sifimoti, ati ní Eṣitemoa; ní Rakali, ní àwọn ìlú Jerameeli, àwọn ìlú Keni, ní Homa, Boraṣani, ati ní Ataki, ní Heburoni ati ní gbogbo ìlú tí Dafidi ati àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ti rìn kiri. Àwọn ará Filistia bá àwọn ọmọ Israẹli jagun ní orí òkè Giliboa. Ọpọlọpọ ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli kú, àwọn yòókù sì sá. Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀ pàápàá sá lójú ogun. Ṣugbọn àwọn ará Filistia lé Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀. Wọ́n pa Jonatani ati Abinadabu ati Malikiṣua, àwọn ọmọ Saulu. Ogun náà le fún Saulu gidigidi, àwọn tafàtafà ta á ní ọfà, ó sì farapa lọpọlọpọ. Ó sọ fún ọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀ pé, “Fa idà rẹ yọ, kí o pa mí, kí àwọn aláìkọlà wọnyi má baà pa mí, kí wọ́n sì fi mí ṣe ẹlẹ́yà.” Ẹ̀rù ba ọmọkunrin náà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, Saulu fa idà rẹ̀ yọ, ó ṣubú lé e lórí, ó sì kú. Nígbà tí ọmọkunrin náà rí i pé Saulu kú, òun náà fa idà rẹ̀ yọ, ó ṣubú lé e lórí ó sì kú. Bẹ́ẹ̀ ni Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀ mẹta, ati ọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀ ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ṣe kú ní ọjọ́ kan náà. Nígbà tí àwọn ọmọ ilẹ̀ Israẹli tí wọn ń gbé òdìkejì àfonífojì Jesireeli ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani, gbọ́ pé àwọn ọmọ ogun Israẹli ti sá lójú ogun, ati pé Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀ ti kú; wọ́n sá kúrò ní ìlú wọn. Àwọn ará Filistia bá lọ tẹ̀dó sibẹ. Ní ọjọ́ keji tí àwọn ará Filistia wá láti bọ́ àwọn nǹkan tí ó wà lára àwọn tí wọ́n kú, wọ́n rí òkú Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀ mẹta ní òkè Giliboa. Wọ́n gé orí Saulu, wọ́n sì bọ́ ihamọra rẹ̀, wọ́n ranṣẹ lọ sí gbogbo ilẹ̀ Filistini, pé kí wọ́n kéde ìròyìn ayọ̀ náà fún gbogbo eniyan ati ní gbogbo ilé oriṣa wọn. Wọ́n kó ihamọra Saulu sílé Aṣitarotu, oriṣa wọn, wọ́n sì kan òkú rẹ̀ mọ́ ara odi Beti Ṣani. Nígbà tí àwọn ará Jabeṣi Gileadi gbọ́ ohun tí àwọn ará Filistia ṣe sí Saulu, àwọn tí wọ́n jẹ́ akọni ninu wọ́n lọ sí Beti Ṣani lóru, wọ́n sì gbé òkú Saulu ati ti àwọn ọmọ rẹ̀ kúrò lára odi Beti Ṣani, wá sí Jabeṣi Gileadi, wọ́n sì sin wọ́n sibẹ. Wọ́n sin egungun wọn sí abẹ́ igi tamarisiki, ní Jabeṣi Gileadi, wọ́n sì gbààwẹ̀ fún ọjọ́ meje. Lẹ́yìn ikú Saulu, nígbà tí Dafidi pada dé láti ojú ogun, níbi tí ó ti ṣẹgun àwọn ará Amaleki, ó dúró ní ìlú Sikilagi fún ọjọ́ meji. Ní ọjọ́ kẹta, ọdọmọkunrin kan wá, láti inú àgọ́ Saulu, ó ti fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì ku erùpẹ̀ sí orí, láti fi ìbànújẹ́ hàn. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Dafidi, ó wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Dafidi bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Níbo ni o ti ń bọ̀?” Ọdọmọkunrin náà dáhùn pé, “Láti inú àgọ́ àwọn ọmọ Israẹli ni mo ti sá àsálà.” Dafidi wí fún un pé, “Sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún mi.” Ọdọmọkunrin náà dáhùn pé, “Sísá ni àwọn ọmọ ogun Israẹli sá kúrò lójú ogun, ọpọlọpọ ninu wọn ni wọ́n sì ti pa; wọ́n ti pa Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀ pẹlu.” Dafidi tún bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Báwo ni o ṣe mọ̀ pé Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀ ti kú?” Ọdọmọkunrin náà dá a lóhùn pé, “Orí òkè Giliboa ni mo wà, ni mo déédé rí Saulu tí ó fara ti ọ̀kọ̀ rẹ̀. Mo sì rí i tí kẹ̀kẹ́ ogun àwọn ọ̀tá ati àwọn ẹlẹ́ṣin wọn ń lépa rẹ̀. Bí ó ti bojú wẹ̀yìn, tí ó rí mi, ó pè mí. Mo sì dá a lóhùn pé, ‘Èmi nìyí.’ Ó bi mí pé, ta ni mí; mo dá a lóhùn pé, ‘Ọ̀kan ninu àwọn ará Amaleki ni mí.’ Saulu bá wí fún mi pé, ‘Sún mọ́ mi níhìn-ín, kí o pa mí, nítorí pé mo ti fara gbọgbẹ́, mò ń jẹ̀rora gidigidi, ṣugbọn ẹ̀mí mi ṣì wà sibẹ.’ Mo bá súnmọ́ Saulu, mo sì pa á. Nítorí mo mọ̀ pé, tí ó bá kúkú ṣubú lulẹ̀, yóo kú náà ni. Mo bá ṣí adé orí rẹ̀, mo sì bọ́ ẹ̀gbà ọrùn ọwọ́ rẹ̀. Àwọn ni mo kó wá fún ọ yìí, Dafidi, oluwa mi.” Ni Dafidi ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá fa aṣọ wọn ya láti fi ìbànújẹ́ wọn hàn. Wọ́n ṣọ̀fọ̀, wọ́n sọkún, wọ́n sì gbààwẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́; nítorí Saulu ati Jonatani, ọmọ rẹ̀, ati àwọn ọmọ Israẹli, eniyan OLUWA nítorí pé ọpọlọpọ wọn ni wọ́n ti pa lójú ogun. Dafidi bèèrè lọ́wọ́ ọdọmọkunrin tí ó wá ròyìn fún un pé, “Níbo ni o ti wá?” Ọdọmọkunrin náà dáhùn pé, “Ọmọ àlejò ará Amaleki kan, tí ń gbé ilẹ̀ Israẹli ni mí.” Dafidi tún bi í pé, “Báwo ni ẹ̀rù kò ṣe bà ọ́ láti pa ọba, ẹni tí OLUWA fi àmì òróró yàn?” Ni Dafidi bá pàṣẹ pé kí ọ̀kan ninu àwọn ọkunrin tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀, lọ pa ọdọmọkunrin ará Amaleki náà. Ọkunrin náà bá pa á. Dafidi wí fún ọdọmọkunrin ará Amaleki náà pé, “Ìwọ ni o fa èyí sí orí ara rẹ. Ìwọ ni o dá ara rẹ lẹ́bi, nípa jíjẹ́wọ́ pé, ìwọ ni o pa ọba, ẹni tí OLUWA fi àmì òróró yàn.” Dafidi bá kọ orin arò fún Saulu, ati Jonatani, ọmọ rẹ̀, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n kọ́ àwọn eniyan Juda ní orin náà. (Àkọsílẹ̀ rẹ̀ wà ninu Ìwé Jaṣari. ) Orin arò náà lọ báyìí: “A! Israẹli, wọ́n ti pa àwọn tí o fi ń ṣògo lórí àwọn òkè rẹ! Ẹ wo bí àwọn akikanju tí ń ṣubú! Ẹ má ṣe sọ nípa rẹ̀ ní Gati, ẹ má ṣe ròyìn rẹ̀ ní ìgboro Aṣikeloni; kí inú àwọn obinrin Filistini má baà dùn, kí àwọn ọmọbinrin àwọn aláìkọlà má baà máa yọ̀. “Ẹ̀yin òkè Giliboa, kí òjò má ṣe rọ̀ le yín lórí, bẹ́ẹ̀ ni kí ìrì má ṣe sẹ̀ sórí yín, kí èso kan má so mọ́ ní gbogbo orí òkè Giliboa, nítorí pé, ibẹ̀ ni apata àwọn akikanju ti dípẹtà; a kò sì fi òróró kun apata Saulu mọ́. Ọrun Jonatani kì í pada lásán, bẹ́ẹ̀ ni idà Saulu kì í pada, láì fi ẹnu kan ẹ̀jẹ̀ àwọn tí ó pa, ati ọ̀rá àwọn akikanju. “Saulu ati Jonatani, àyànfẹ́ ati eniyan rere, wọn kì í ya ara wọn nígbà ayé wọn, nígbà tí ikú sì dé, wọn kò ya ara wọn. Wọ́n yára ju àṣá lọ, wọ́n sì lágbára ju kinniun lọ. “Ẹ̀yin obinrin Israẹli, ẹ sọkún nítorí Saulu, ẹni tí ó ro yín ní aṣọ elése àlùkò, tí ó sì fi ohun ọ̀ṣọ́ wúrà ṣe yín lọ́ṣọ̀ọ́. “Ẹ wo bí àwọn akikanju tí ń ṣubú lójú ogun! Jonatani ti ṣubú lulẹ̀, wọ́n ti pa á lórí òkè. “Mò ń ṣe ìdárò rẹ, Jonatani arakunrin mi; o ṣọ̀wọ́n fún mi lọpọlọpọ. Ìfẹ́ tí o ní sí mi, kò ṣe é fi ẹnu sọ, ó ju ìfẹ́ obinrin lọ. “Ẹ wo bí àwọn akikanju tí ń ṣubú, tí àwọn ohun ìjà ogun sì ń ṣègbé!” Lẹ́yìn èyí, Dafidi bèèrè lọ́wọ́ OLUWA pé, “OLUWA, ṣé kí ń lọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú Juda?” OLUWA sì dá a lóhùn pé, “Lọ.” Dafidi bá tún bèèrè pé, “Ìlú wo ni kí n lọ?” OLUWA ní, “Lọ sí ìlú Heburoni.” Dafidi bá mú àwọn iyawo rẹ̀ mejeeji; Ahinoamu ará Jesireeli, ati Abigaili, opó Nabali, ará Kamẹli lọ́wọ́ lọ. Ó kó àwọn ọkunrin tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ pẹlu, ati gbogbo ìdílé wọn, wọ́n sì ń gbé àwọn ìlú tí wọ́n wà ní agbègbè Heburoni. Lẹ́yìn náà, àwọn ará Juda wá sí Heburoni, wọ́n fi òróró yan Dafidi ní ọba wọn. Nígbà tí Dafidi gbọ́ pé àwọn ará Jabeṣi Gileadi ni wọ́n sin òkú Saulu, ó ranṣẹ sí wọn pé, “Kí OLUWA bukun yín nítorí pé ẹ ṣe olóòótọ́ sí Saulu ọba wa, ẹ sì sin òkú rẹ̀. Kí OLUWA fi ìfẹ́ ńlá ati òdodo rẹ̀ hàn fun yín. Èmi náà yóo ṣe yín dáradára, nítorí ohun tí ẹ ṣe yìí. Nítorí náà, ẹ mọ́kàn gírí kí ẹ sì ṣe akin; nítorí pé Saulu, oluwa yín ti kú, àwọn eniyan Juda sì ti fi òróró yàn mí gẹ́gẹ́ bí ọba wọn.” Abineri ọmọ Neri, tíí ṣe balogun àwọn ọmọ ogun Saulu, gbé Iṣiboṣẹti ọmọ Saulu sá lọ sí Mahanaimu ní òdìkejì odò Jọdani. Níbẹ̀ ni ó ti fi Iṣiboṣẹti jọba lórí gbogbo agbègbè Gileadi, Aṣuri, Jesireeli, Efuraimu, Bẹnjamini, ati lórí gbogbo ilẹ̀ Israẹli. Ẹni ogoji ọdún ni nígbà tí wọ́n fi jọba lórí Israẹli, ó sì wà lórí oyè fún ọdún meji. Ṣugbọn ẹ̀yìn Dafidi ni gbogbo ẹ̀yà Juda wà. Ọdún meje ààbọ̀ ni Dafidi fi jọba lórí ẹ̀yà Juda ní ìlú Heburoni. Abineri ọmọ Neri ati àwọn iranṣẹ Iṣiboṣẹti, ọmọ Saulu, ṣígun láti Mahanaimu, lọ sí ìlú Gibeoni. Joabu, tí orúkọ ìyá rẹ̀ ń jẹ́ Seruaya, ati àwọn iranṣẹ Dafidi yòókù lọ pàdé wọn níbi adágún Gibeoni. Àwọn tí wọ́n tẹ̀lé Joabu jókòó sí ẹ̀gbẹ́ kan adágún náà, àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn Abineri náà sì jókòó sí òdìkejì. Abineri bá sọ fún Joabu pé, “Jẹ́ kí àwọn bíi mélòó kan ninu àwọn ọmọkunrin láti ẹ̀gbẹ́ kinni keji bọ́ siwaju, kí wọ́n fi ohun ìjà dánrawò níwájú wa.” Joabu sì gbà bẹ́ẹ̀. Àwọn mejila bá jáde láti ẹ̀gbẹ́ kinni keji; àwọn mejila ẹ̀gbẹ́ kan dúró fún ẹ̀yà Bẹnjamini ati Iṣiboṣẹti ọmọ Saulu, wọ́n sì bá àwọn iranṣẹ Dafidi mejila, tí wọ́n jáde láti inú ẹ̀yà Juda jà. Ẹnìkọ̀ọ̀kan láti ẹ̀gbẹ́ kinni, dojú kọ ẹnìkọ̀ọ̀kan láti ẹ̀gbẹ́ keji, wọ́n sì gbá ara wọn lórí mú. Ẹnìkínní ti idà rẹ̀ bọ ẹnìkejì rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́, àwọn mẹrẹẹrinlelogun ṣubú lulẹ̀, wọ́n sì kú. Ìdí nìyí tí wọ́n fi sọ ibẹ̀ ní Helikati-hasurimu. Ìtumọ̀ rẹ̀ ni “Pápá Idà”; ó wà ní Gibeoni. Ogun gbígbóná bẹ́ sílẹ̀ ní ọjọ́ náà, ṣugbọn àwọn eniyan Dafidi ṣẹgun Abineri ati àwọn eniyan Israẹli. Àwọn ọmọ Seruaya mẹtẹẹta, Joabu, Abiṣai, ati Asaheli, wà lójú ogun náà. Ẹsẹ̀ Asaheli yá nílẹ̀ pupọ, àfi bí ẹsẹ̀ àgbọ̀nrín. Asaheli bẹ̀rẹ̀ sí lé Abineri lọ, bí ó sì ti ń lé e lọ, kò wo ọ̀tún, bẹ́ẹ̀ ni kò wo òsì. Abineri bá bojúwo ẹ̀yìn, ó bèèrè pé, “Asaheli, ṣé ìwọ ni ò ń lé mi?” Asaheli sì dá a lóhùn pé, “Èmi ni.” Abineri wí fún un pé, “Yà sí ọ̀tún, tabi sí òsì, kí o mú ọ̀kan ninu àwọn ọdọmọkunrin, kí o sì kó gbogbo ìkógun rẹ̀.” Ṣugbọn Asaheli kọ̀, kò yipada kúrò lẹ́yìn rẹ̀. Abineri tún pe Asaheli, ó tún sọ fún un pé, “Pada lẹ́yìn mi, má jẹ́ kí n pa ọ́? Ojú wo ni o sì fẹ́ kí n fi wo Joabu ẹ̀gbọ́n rẹ?” Ṣugbọn Asaheli kọ̀, kò pada. Abineri bá sọ ọ̀kọ̀ ní àsọsẹ́yìn, ọ̀kọ̀ sì lọ bá Asaheli ní ikùn, ọ̀kọ̀ náà sì yọ jáde lẹ́yìn rẹ̀. Asaheli wó lulẹ̀, ó sì kú síbi tí ó ṣubú sí. Gbogbo àwọn tí wọ́n bá ti dé ibi tí Asaheli kú sí, ni wọ́n ń dúró. Ṣugbọn Joabu ati Abiṣai ń lé Abineri lọ, bí oòrùn ti ń lọ wọ̀, wọ́n dé ara òkè Ama tí ó wà níwájú Gia ní ọ̀nà aṣálẹ̀ Gibeoni. Àwọn ọmọ ogun yòókù láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini kó ara wọn jọ sẹ́yìn Abineri, wọ́n sì dúró káàkiri lórí òkè, pẹlu ìmúra ogun. Lẹ́yìn náà Abineri pe Joabu, ó ní, “Ṣé títí lae ni a óo máa ja ìjà yìí lọ ni? Àbí ìwọ náà kò rí i pé, bí a bá ja ogun yìí títí a fi pa ara wa tán, kò sí nǹkankan tí ẹnikẹ́ni yóo rí gbà, àfi ọ̀tá! Nígbà wo ni o fẹ́ dúró dà, kí o tó dá àwọn eniyan rẹ lẹ́kun pé kí wọ́n yé lépa àwọn arakunrin wọn?” Joabu bá dáhùn pé, “Ọlọrun mọ̀, bí o bá dákẹ́ tí o kò sọ̀rọ̀ ni, àwọn eniyan mi kì bá máa le yín lọ títí di òwúrọ̀ ọ̀la.” Joabu bá fọn fèrè ogun, láti fi pe àwọn eniyan rẹ̀ pada. Nígbà náà ni wọ́n tó pada lẹ́yìn àwọn eniyan Israẹli, tí wọ́n sì dáwọ́ ogun dúró. Gbogbo òru ọjọ́ náà ni Abineri ati àwọn eniyan rẹ̀ fi ń rìn pada lọ ní àfonífojì Jọdani, wọ́n kọjá sí òdìkejì odò Jọdani. Gbogbo òwúrọ̀ ọjọ́ keji ni wọ́n sì fi rìn kí wọ́n tó pada dé Mahanaimu. Nígbà tí Joabu pada lẹ́yìn Abineri, tí ó sì kó gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ jọ, ó rí i pé, lẹ́yìn Asaheli, àwọn mejidinlogun ni wọn kò rí mọ́. Ṣugbọn àwọn eniyan Dafidi ti pa ọtalelọọdunrun (360) ninu àwọn eniyan Abineri. Joabu ati àwọn eniyan rẹ̀ bá gbé òkú Asaheli, wọ́n sì lọ sin ín sí ibojì ìdílé wọn ní Bẹtilẹhẹmu. Gbogbo òru ọjọ́ náà ni wọ́n fi rìn; ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, ni wọ́n pada dé Heburoni. Àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn ìdílé Saulu, ati àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn ìdílé Dafidi bá ara wọn jagun fún ìgbà pípẹ́. Bí agbára Dafidi ti ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni agbára àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn Saulu ń dínkù. Ọmọkunrin mẹfa ni wọ́n bí fún Dafidi nígbà tí ó wà ní Heburoni. Aminoni tí ìyá rẹ̀ ń jẹ́ Ahinoamu, ará Jesireeli, ni àkọ́bí. Ekeji ni Kileabu, ọmọ Abigaili, opó Nabali, ará Kamẹli. Ẹkẹta ni Absalomu, ọmọ Maaka, ọmọ Talimai, ọba Geṣuri. Ẹkẹrin ni Adonija ọmọ Hagiti. Ẹkarun-un ni Ṣefataya ọmọ Abitali. Ẹkẹfa sì ni Itireamu, ọmọ Egila. Heburoni ni wọ́n ti bí àwọn ọmọ náà fún Dafidi. Ní àkókò tí ogun wà láàrin àwọn eniyan Dafidi ati àwọn eniyan Saulu, agbára Abineri bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ sí i láàrin àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn Saulu. Ní ọjọ́ kan, Iṣiboṣẹti ọmọ Saulu fi ẹ̀sùn kan Abineri pé ó bá obinrin Saulu kan, tí wọn ń pè ní Risipa, ọmọ Aya, lòpọ̀. Ọ̀rọ̀ náà bí Abineri ninu gidigidi, ó bi Iṣiboṣẹti pé, “Ṣé o rò pé mo jẹ́ hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí Saulu laelae? Àbí ẹ̀yìn àwọn ará Juda ni ẹ rò pé mo wà ni? Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni mo ti jẹ́ olóòótọ́ sí Saulu baba rẹ, àwọn arakunrin rẹ̀ ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, èmi ni n kò sì ti jẹ́ kí apá Dafidi ká ọ. Ṣugbọn lónìí ńkọ́, ò ń fi ẹ̀sùn kàn mí nípa obinrin. Kí Ọlọrun lù mí pa, bí n kò bá ṣe gbogbo ohun tí ó wà ní ìkáwọ́ mi, láti mú ìlérí tí OLUWA ṣe fún Dafidi ṣẹ, pé, òun yóo gba ìjọba kúrò lọ́wọ́ ìdílé Saulu, yóo sì fi Dafidi jọba lórí Juda jákèjádò, láti Dani títí dé Beeriṣeba.” Iṣiboṣẹti kò sì lè dá Abineri lóhùn nítorí ó bẹ̀rù rẹ̀. Abineri bá ranṣẹ sí Dafidi ní Heburoni pé, “Ṣebí ìwọ ni o ni ilẹ̀ yìí? Bá mi dá majẹmu, n óo wà lẹ́yìn rẹ, n óo sì mú kí gbogbo Israẹli pada sọ́dọ̀ rẹ.” Dafidi bá dáhùn pé, “Ó dára, n óo bá ọ dá majẹmu. Ṣugbọn nǹkankan ni mo fẹ́ kí o ṣe, o kò ní fi ojú kàn mí, àfi bí o bá mú Mikali ọmọbinrin Saulu lọ́wọ́ nígbà tí o bá ń bọ̀ wá rí mi.” Dafidi bá rán àwọn oníṣẹ́ kan sí Iṣiboṣẹti, ọmọ Saulu, pé kí ó dá Mikali, aya òun, tí òun san ọgọrun-un awọ orí adọ̀dọ́ àwọn ará Filistia lé lórí pada fún òun. Iṣiboṣẹti bá ranṣẹ lọ gba Mikali lọ́wọ́ Palitieli, ọmọ Laiṣi, ọkọ rẹ̀. Ṣugbọn bí ó ti ń lọ ni ọkọ rẹ̀ ń sọkún tẹ̀lé e títí tí ó fi dé Bahurimu, ibẹ̀ ni Abineri ti dá a pada, ó sì pada. Abineri tọ àwọn àgbààgbà Israẹli lọ, ó ní, “Ó pẹ́ tí ẹ ti fẹ́ kí Dafidi jẹ́ ọba yín. Àkókò nìyí láti ṣe ohun tí ẹ ti fẹ́ ṣe, nítorí pé OLUWA ti ṣe ìlérí fún Dafidi pé Dafidi ni òun óo lò láti gba àwọn ọmọ Israẹli kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Filistia ati gbogbo àwọn ọ̀tá wọn yòókù.” Abineri bá àwọn ará Bẹnjamini sọ̀rọ̀ pẹlu. Lẹ́yìn náà ó lọ bá Dafidi ní Heburoni láti sọ ohun tí àwọn ará Bẹnjamini ati gbogbo ọmọ Israẹli ti gbà láti ṣe fún Dafidi. Nígbà tí Abineri dé ọ̀dọ̀ Dafidi ní Heburoni pẹlu ogún ọkunrin tí ń bá a lọ, Dafidi se àsè ńlá fún wọn. Abineri bá sọ fún Dafidi pé, “N óo lọ, n óo wá ọ̀nà tí gbogbo Israẹli yóo fi wà lẹ́yìn rẹ, oluwa mi, (ọba), tí wọn yóo bá ọ dá majẹmu tí o óo sì jọba lórí gbogbo ibi tí ọkàn rẹ bá fẹ́.” Dafidi ní kí ó máa lọ, ó sì lọ ní alaafia. Kò pẹ́ pupọ lẹ́yìn náà, ni Joabu ati àwọn ọmọ ogun Dafidi pada dé láti ibi tí wọ́n ti lọ ja ogun kan, wọ́n sì kó ọpọlọpọ ìkógun bọ̀. Ṣugbọn Abineri kò sí lọ́dọ̀ Dafidi, ní Heburoni, nígbà tí wọ́n dé, nítorí pé Dafidi ti ní kí ó máa pada lọ, ó sì ti lọ ní alaafia. Nígbà tí Joabu ati àwọn ọmọ ogun tí wọ́n tẹ̀lé e dé, wọ́n sọ fún Joabu pé, “Abineri ti wá sí ọ̀dọ̀ Dafidi ọba, ọba sì ti jẹ́ kí ó lọ ní alaafia.” Joabu bá lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, ó bèèrè pé, “Irú kí ni o ṣe yìí, Abineri wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, o sì jẹ́ kí ó lọ bẹ́ẹ̀? Ṣebí o mọ̀ pé ó wá tàn ọ́ jẹ ni? Ó wá fi ọgbọ́n wádìí gbogbo ibi tí ò ń lọ, ati gbogbo ohun tí ò ń ṣe ni.” Nígbà tí Joabu kúrò lọ́dọ̀ Dafidi, ó ranṣẹ lọ pe Abineri, wọ́n sì dá a pada láti ibi kànga Sira, ṣugbọn Dafidi kò mọ nǹkankan nípa rẹ̀. Nígbà tí Abineri pada dé Heburoni, Joabu mú un lọ sí kọ̀rọ̀ kan, níbi ẹnubodè, bí ẹni pé ó fẹ́ bá a sọ ọ̀rọ̀ àṣírí, Joabu bá fi nǹkan gún un ní ikùn. Bẹ́ẹ̀ ni Abineri ṣe kú, nítorí pé ó pa Asaheli arakunrin Joabu. Nígbà tí Dafidi gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó ní, “OLUWA mọ̀ pé, èmi ati àwọn eniyan mi kò lọ́wọ́ sí ikú Abineri rárá, ọwọ́ wa mọ́ patapata ninu ọ̀ràn náà. Orí Joabu ati ìdílé baba rẹ̀ ni ẹ̀bi ìjìyà ikú yìí yóo dà lé. Láti ìrandíran rẹ̀, kò ní sí ẹnikẹ́ni tí kò ní kó àtọ̀sí, tabi kí ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀, tabi tí kò ní jẹ́ pé iṣẹ́ obinrin nìkan ni wọn yóo lè ṣe, tabi kí wọ́n pa wọ́n lójú ogun, tabi kí wọ́n máa tọrọ jẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni Joabu ati Abiṣai, arakunrin rẹ̀, ṣe pa Abineri tí wọ́n sì gbẹ̀san ikú Asaheli, arakunrin wọn, tí Abineri pa lójú ogun Gibeoni. Dafidi pàṣẹ pé kí Joabu ati àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ fa aṣọ wọn ya, kí wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ Abineri. Nígbà tí ó tó àkókò láti sìnkú Abineri, Dafidi ọba pàápàá tẹ̀lé òkú rẹ̀. Heburoni ni wọ́n sin òkú Abineri sí, ọba sọkún létí ibojì rẹ̀, gbogbo àwọn eniyan sì sọkún pẹlu. Dafidi kọ orin arò kan fún Abineri báyìí pé: “Kí ló dé tí Abineri fi kú bí aṣiwèrè? Wọn kò dì ọ́ lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dì ọ́ lẹ́sẹ̀; o ṣubú bí ìgbà tí eniyan ṣubú níwájú ìkà.” Gbogbo eniyan sì tún bú sẹ́kún. Gbogbo eniyan rọ Dafidi, pé kí ó jẹun ní ọ̀sán ọjọ́ náà ṣugbọn ó búra pé kí Ọlọrun pa òun bí òun bá fi ẹnu kan nǹkankan títí tí ilẹ̀ yóo fi ṣú. Gbogbo àwọn eniyan ṣe akiyesi ohun tí ọba ṣe yìí, ó sì dùn mọ́ wọn. Gbogbo ohun tí ọba ṣe patapata ni ó dùn mọ́ àwọn eniyan. Gbogbo àwọn eniyan Dafidi, ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni ó hàn sí gbangba pé, ọba kò lọ́wọ́ ninu pípa tí wọ́n pa Abineri. Ọba bi àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ṣé ẹ kò mọ̀ pé eniyan ńlá, ati alágbára kan ni ó ṣubú lónìí, ní ilẹ̀ Israẹli?” Ó ní, “Agbára mi dínkù lónìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òróró ni a fi yàn mí ní ọba. Ìwà ipá àwọn ọmọ Seruaya yìí ti le jù fún mi. OLUWA nìkan ni ó lè san ẹ̀san fún eniyan burúkú gẹ́gẹ́ bí ìwà ìkà rẹ̀.” Nígbà tí Iṣiboṣẹti ọmọ Saulu gbọ́ pé wọ́n ti pa Abineri ní Heburoni, ẹ̀rù bà á gidigidi, ìdààmú sì bá gbogbo àwọn ọmọ Israẹli. Iṣiboṣẹti ní àwọn ìjòyè meji kan, tí wọ́n jẹ́ aṣaaju fún àwọn tí wọ́n máa ń dánà káàkiri. Orúkọ ekinni ni Baana, ti ekeji sì ni Rekabu, ọmọ Rimoni, ará Beeroti, ti ẹ̀yà Bẹnjamini. (Ẹ̀yà Bẹnjamini ni wọ́n ka Beeroti kún.) Àwọn ará Beeroti ti sá lọ sí Gitaimu, ibẹ̀ ni wọ́n sì ń gbé títí di òní olónìí. Jonatani ọmọ Saulu ní ọmọkunrin kan, tí ó yarọ, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mẹfiboṣẹti. Ọmọ ọdún marun-un ni, nígbà tí wọ́n mú ìròyìn ikú Saulu ati ti Jonatani wá, láti ìlú Jesireeli; ni olùtọ́jú rẹ̀ bá gbé e sá kúrò. Ibi tí ó ti ń fi ìkánjú gbé ọmọ náà sá lọ, ó já ṣubú, ó sì fi bẹ́ẹ̀ yarọ. Ní ọjọ́ kan, Rekabu ati Baana, àwọn ọmọ Rimoni ará Beeroti, gbéra, wọ́n lọ sí ilé Iṣiboṣẹti, wọ́n débẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀sán, ní àkókò tí Iṣiboṣẹti ń sun oorun ọ̀sán lọ́wọ́. Oorun ti gbé obinrin tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà, tí ń fẹ́ ọkà lọ́wọ́ lọ, ó sùn lọ fọnfọn. Rekabu ati Baana bá rọra yọ́ wọlé. Nígbà tí wọ́n wọlé, wọ́n bá a níbi tí ó sùn sí lórí ibùsùn ninu yàrá rẹ̀, wọ́n lù ú pa, wọ́n sì gé orí rẹ̀. Wọ́n gbé orí rẹ̀, wọ́n gba ọ̀nà àfonífojì odò Jọdani lọ, wọ́n sì fi gbogbo òru ọjọ́ náà rìn. Nígbà tí wọ́n dé Heburoni, wọ́n gbé orí rẹ̀ tọ Dafidi ọba lọ, wọ́n sì wí fún un pé, “Orí Iṣiboṣẹti, ọmọ Saulu, ọ̀tá rẹ, tí ó ń wá ọ̀nà láti pa ọ́ nìyí; oluwa mi, ọba, OLUWA ti mú kí ó ṣeéṣe láti gbẹ̀san, lára Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀.” Ṣugbọn Dafidi dá wọn lóhùn pé, “OLUWA tí ó ti ń yọ mí ninu gbogbo ewu, ni mo fi búra pé, ẹni tí ó wá ròyìn ikú Saulu fún mi ní Sikilagi rò pé ìròyìn ayọ̀ ni òun mú wá fún mi, ṣugbọn mo ní kí wọn mú un kí wọ́n pa á. Ó jẹ èrè ìròyìn ayọ̀ rẹ̀, tí ó mú wá fún mi. Báwo ni yóo ti burú tó fún àwọn ẹni ibi, tí wọ́n pa aláìṣẹ̀ sórí ibùsùn ninu ilé rẹ̀? Ṣé n kò ní gbẹ̀san pípa tí ẹ pa á lára yín, kí n sì pa yín rẹ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé?” Dafidi pàṣẹ fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n sì pa Rekabu ati Baana. Wọ́n gé ọwọ́ wọn, ati ẹsẹ̀ wọn, wọ́n sì so wọ́n kọ́ lẹ́bàá adágún tí ó wà ní Heburoni. Wọ́n gbé orí Iṣiboṣẹti, wọ́n sì sin ín sí ibojì Abineri ní Heburoni. Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ẹ̀yà Israẹli tọ Dafidi lọ ní Heburoni, wọ́n sọ fún un pé, “Ara kan náà ni wá, ẹ̀jẹ̀ kan náà sì ni gbogbo wa. Látẹ̀yìn wá, nígbà tí Saulu pàápàá wà lórí oyè, ìwọ ni o máa ń kó àwọn ọmọ Israẹli lọ sógun. OLUWA sì ti ṣèlérí fún ọ pé, ìwọ ni o óo jẹ́ aṣiwaju àwọn eniyan rẹ̀, ati ọba wọn.” Gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli wá sí ọ̀dọ̀ ọba ní Heburoni, Dafidi ọba sì bá wọn dá majẹmu níbẹ̀ níwájú OLUWA. Wọ́n bá fi òróró yan Dafidi ní ọba lórí Israẹli. Ẹni ọgbọ̀n ọdún ni, nígbà tí ó gorí oyè, ó sì jọba fún ogoji ọdún. Ọdún meje ati oṣù mẹfa ni ó fi jọba lórí ẹ̀yà Juda ní Heburoni. Lẹ́yìn náà, ó wá sí Jerusalẹmu ó sì jọba lórí gbogbo Israẹli ati Juda fún ọdún mẹtalelọgbọn. Nígbà tí ó yá, Dafidi ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti ìlú Jerusalẹmu. Àwọn ará Jebusi tí wọn ń gbé ibẹ̀ nígbà náà wí fún Dafidi pé, “O kò lè wọ inú ìlú yìí wá, àwọn afọ́jú ati àwọn arọ lásán ti tó láti lé ọ dànù.” Wọ́n lérò pé Dafidi kò le ṣẹgun ìlú náà. Ṣugbọn Dafidi jagun gba Sioni, ìlú olódi wọn. Sioni sì di ibi tí wọn ń pè ní ìlú Dafidi. Dafidi bá sọ fún àwọn eniyan rẹ̀ ní ọjọ́ náà pé, “Jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ pa àwọn ará Jebusi gba ojú àgbàrá lọ pa àwọn afọ́jú ati àwọn arọ tí ọkàn Dafidi kórìíra.” (Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń wí pé, “Àwọn afọ́jú ati àwọn arọ kò ní lè wọ ilé OLUWA.”) Lẹ́yìn tí Dafidi ti ṣẹgun ìlú olódi náà, ó ń gbé inú rẹ̀, ó sì yí orúkọ ibẹ̀ pada sí “Ìlú Dafidi”. Ó kọ́ ìlú náà yíká, bẹ̀rẹ̀ láti Milo, níbi tí wọ́n ti kún ilẹ̀ ní ìhà ìwọ̀ oòrùn òkè náà. Agbára Dafidi bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ sí i, nítorí pé OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun wà pẹlu rẹ̀. Hiramu ọba Tire rán àwọn oníṣẹ́ sí Dafidi. Ó fi igi Kedari ranṣẹ sí i, pẹlu àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, ati àwọn tí wọn ń fi òkúta kọ́ ilé, pé kí wọ́n lọ kọ́ ààfin Dafidi. Dafidi wá mọ̀ pé, OLUWA ti fi ìdí òun múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọba Israẹli, ó sì ti gbé ìjọba òun ga, nítorí Israẹli, àwọn eniyan rẹ̀. Nígbà tí Dafidi kúrò ní Heburoni lọ sí Jerusalẹmu, ó fẹ́ àwọn obinrin mìíràn kún àwọn aya rẹ̀. Ó sì ní ọpọlọpọ ọmọ sí i, lọkunrin ati lobinrin. Orúkọ àwọn tí wọ́n bí fún un ní Jerusalẹmu nìwọ̀nyí: Ṣamua ati Ṣobabu, Natani, ati Solomoni; Ibihari ati Eliṣua, Nefegi ati Jafia; Eliṣama, Eliada, ati Elifeleti. Nígbà tí àwọn ará Filistia gbọ́ pé wọ́n ti fi Dafidi jọba Israẹli, gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn jáde lọ láti mú un, ṣugbọn Dafidi gbọ́ pé wọ́n ń bọ̀ wá mú òun, ó bá lọ sí ibi ààbò. Nígbà tí àwọn ará Filistia dé ibi àfonífojì Refaimu, wọ́n dúró níbẹ̀. Dafidi bi OLUWA pé, “Ṣé kí n kọlu àwọn ará Filistia, ṣé o óo fún mi ní ìṣẹ́gun lórí wọn?” OLUWA dá a lóhùn pé, “Kọlù wọ́n, n óo fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí wọn.” Dafidi bá wá sí Baali Perasimu, ó sì ṣẹgun àwọn ará Filistia níbẹ̀. Ó ní, “Bí ìkún omi tí í ya bèbè rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA fọ́n àwọn ọ̀tá mi ká níwájú mi.” Ó bá pe orúkọ ibẹ̀ ní Baali Perasimu. Níbi tí àwọn ará Filistia ti ń sá lọ, wọ́n gbàgbé àwọn oriṣa wọn sílẹ̀, Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ sì kó wọn lọ. Àwọn ará Filistia pada, wọ́n tún dúró sí àfonífojì Refaimu. Dafidi tún tọ OLUWA lọ láti bèèrè ohun tí yóo ṣe. OLUWA dá a lóhùn pé, “Má ṣe kọlù wọ́n níhìn-ín, ṣugbọn múra, kí o yípo lọ sẹ́yìn wọn, kí o sì kọlù wọ́n ní apá òdìkejì àwọn igi basamu. Nígbà tí o bá gbọ́ ìró kan, tí ó bá dàbí ẹni pé, eniyan ń fi ẹsẹ̀ kilẹ̀ lọ lórí àwọn igi, ni kí o tó kọlù wọ́n, nítorí pé, OLUWA ti kọjá lọ níwájú rẹ láti ṣẹgun àwọn ọmọ ogun Filistini.” Dafidi ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún un, ó sì pa àwọn ọmọ ogun Filistini láti Geba títí dé Geseri. Dafidi tún pe gbogbo àwọn akikanju ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli jọ; wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaarun (30,000). Ó kó wọn lọ sí Baala ní Juda láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọrun wá sí Jerusalẹmu. Orúkọ OLUWA àwọn ọmọ ogun ni wọ́n fi ń pe àpótí ẹ̀rí náà, ìtẹ́ rẹ̀ sì wà lórí àwọn Kerubu tí ó wà lókè àpótí náà. Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí jáde kúrò ní ilé Abinadabu tí ó wà lórí òkè, wọ́n sì gbé e ka orí kẹ̀kẹ́ tuntun kan. Usa ati Ahio ọmọ Abinadabu sì ń ti kẹ̀kẹ́ náà; Ahio ni ó ṣáájú rẹ̀. Dafidi ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí jó níwájú OLUWA, wọ́n sì ń kọrin pẹlu gbogbo agbára wọn. Wọ́n ń lu àwọn ohun èlò orin olókùn tí wọ́n ń pè ní hapu, ati lire; ati ìlù, ati ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ ati aro. Bí wọ́n ti dé ibi ìpakà Nakoni, àwọn mààlúù tí ń fa kẹ̀kẹ́ tí àpótí ẹ̀rí wà lórí rẹ̀ kọsẹ̀, Usa bá yára di àpótí ẹ̀rí náà mú. Inú bí OLUWA sí Usa, OLUWA sì lù ú pa nítorí pé ó fi ọwọ́ kan àpótí ẹ̀rí náà. Usa kú sẹ́gbẹ̀ẹ́ àpótí ẹ̀rí náà. Inú bí Dafidi gidigidi nítorí pé OLUWA lu Usa pa. Láti ìgbà náà ni wọ́n ti ń pe ibẹ̀ ní Peresi Usa, títí di òní olónìí. Ẹ̀rù OLUWA ba Dafidi ní ọjọ́ náà, ó sì wí pé, “Báwo ni n óo ṣe gbé àpótí ẹ̀rí OLUWA wá sọ́dọ̀ mi?” Ọkàn rẹ̀ bá yipada, ó pinnu pé òun kò ní gbé e lọ sí Jerusalẹmu, ìlú Dafidi mọ́. Dípò bẹ́ẹ̀, ó gbé e lọ sí ilé Obedi Edomu, ará ìlú Gati. Àpótí ẹ̀rí OLUWA náà wà níbẹ̀ fún oṣù mẹta, OLUWA sì bukun Obedi Edomu ati ìdílé rẹ̀. Wọ́n bá lọ sọ fún Dafidi pé, “OLUWA ti bukun Obedi Edomu, ati gbogbo ohun tí ó ní, nítorí pé àpótí ẹ̀rí OLUWA wà ní ilé rẹ̀.” Dafidi bá lọ gbé àpótí ẹ̀rí náà kúrò ní ilé rẹ̀ wá sí Jerusalẹmu, pẹlu àjọyọ̀ ńlá. Lẹ́yìn tí àwọn tí wọ́n ru àpótí ẹ̀rí náà ti gbé ìṣísẹ̀ mẹfa, Dafidi dá wọn dúró, ó sì fi akọ mààlúù kan ati ọmọ mààlúù àbọ́pa kan rúbọ sí OLUWA. Dafidi sán aṣọ mọ́dìí, ó sì ń jó pẹlu gbogbo agbára níwájú OLUWA. Bẹ́ẹ̀ ni ọba ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ṣe gbé àpótí ẹ̀rí OLUWA wọ Jerusalẹmu, pẹlu ìhó ayọ̀ ati ìró fèrè. Bí wọ́n ti gbé àpótí ẹ̀rí náà wọ inú ìlú Dafidi, Mikali ọmọ Saulu yọjú wo òde láti ojú fèrèsé, ó rí Dafidi ọba tí ó ń jó tí ó sì ń fò sókè níwájú OLUWA, Mikali sì kẹ́gàn rẹ̀ ninu ọkàn rẹ̀. Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí náà wọnú ìlú, wọ́n sì gbé e sí ààyè rẹ̀, ninu àgọ́ tí Dafidi ti kọ́ sílẹ̀ fún un. Dafidi sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia sí OLUWA. Nígbà tí ó rú ẹbọ tán, ó súre fún àwọn eniyan náà ní orúkọ OLUWA àwọn ọmọ ogun. Ó sì pín oúnjẹ fún gbogbo wọn, lọkunrin ati lobinrin. Ó fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ní ìṣù àkàrà kọ̀ọ̀kan, ati ègé ẹran kọ̀ọ̀kan, ati àkàrà tí wọ́n fi èso resini sí ninu. Lẹ́yìn náà, olukuluku lọ sí ilé. Nígbà tí wọ́n parí, Dafidi pada sí ilé láti súre fún àwọn ará ilé rẹ̀. Mikali, ọmọ Saulu, bá lọ pàdé rẹ̀, ó ní, “Ọba Israẹli mà dárà lónìí! Ọba yán gbogbo aṣọ kúrò lára, bí aláìlóye eniyan níwájú àwọn iranṣẹbinrin àwọn iranṣẹ rẹ̀!” Dafidi dá a lóhùn pé, “Ijó ni mò ń jó, níwájú OLUWA tí ó yàn mí dípò baba rẹ ati gbogbo ìdílé rẹ̀, láti fi mí ṣe alákòóso Israẹli, àwọn eniyan OLUWA. N óo tún máa jó níwájú OLUWA. Kékeré ni èyí tí mo ṣe yìí, n óo máa ṣe jù bí mo ti ṣe yìí lọ. N kò ní jẹ́ nǹkankan lójú rẹ, ṣugbọn àwọn iranṣẹbinrin tí o sọ nípa wọn yìí, yóo bu ọlá fún mi.” Mikali, ọmọbinrin Saulu, kò sì bímọ títí ó fi kú. Lẹ́yìn tí Dafidi ọba ti bẹ̀rẹ̀ sí gbé inú ààfin rẹ̀, tí OLUWA ti fi ọkàn rẹ̀ balẹ̀, tí ó sì dáàbò bò ó lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀, ọba wí fún Natani wolii pé, “Èmi ń gbé inú ààfin tí wọ́n fi igi kedari kọ́, ṣugbọn inú àgọ́ ni àpótí ẹ̀rí OLUWA wà!” Natani dá a lóhùn pé, “Ṣe ohunkohun tí ó bá wà ní ọkàn rẹ, nítorí pé OLUWA wà pẹlu rẹ.” Ṣugbọn ní òru ọjọ́ náà, OLUWA wí fún Natani pé, “Lọ sọ fún Dafidi iranṣẹ mi, pé, báyìí ni OLUWA wí, ‘Ṣé o fẹ́ kọ́ ilé fún mi láti máa gbé ni? Láti ìgbà tí mo ti gba àwọn ọmọ Israẹli kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti títí di àkókò yìí, n kò fi ìgbà kan gbé inú ilé rí, inú àgọ́ ni mò ń gbé káàkiri. Ninu gbogbo bí mo ti ṣe ń bá àwọn ọmọ Israẹli kiri, ǹjẹ́ mo bèèrè lọ́wọ́ ọ̀kan ninu àwọn olórí wọn tí mo yàn láti jẹ́ alákòóso àwọn eniyan mi, pé, Kí ló dé tí wọn kò fi igi kedari kọ́ ilé fún mi?’ “Nítorí náà, sọ fún Dafidi iranṣẹ mi pé, ‘Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo mú un kúrò níbi tí ó ti ń ṣọ́ àwọn aguntan, ninu pápá, mo sì fi jọba Israẹli, àwọn eniyan mi. Mo wà pẹlu rẹ̀ ní gbogbo ibi tí ó lọ, mo sì ń ṣẹgun gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ fún un, bí ó ti ń tẹ̀síwájú. N óo sọ ọ́ di olókìkí bí ọba tí ó lágbára jùlọ láyé. N óo yan ibìkan fún Israẹli, àwọn eniyan mi, n óo sì fìdí wọn múlẹ̀ níbẹ̀. Wọn yóo máa gbé ilẹ̀ wọn, ẹnikẹ́ni kò sì ní ni wọ́n lára, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹni ibi kò ní yọ wọ́n lẹ́nu mọ́ bíi ti ìgbà tí mo yan àwọn onídàájọ́ fún Israẹli, àwọn eniyan mi. N óo fún un ní ìsinmi kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀.’ OLUWA sì tún tẹnu mọ́ ọn fún un pé, ‘Èmi fúnra mi ni n óo sọ ìdílé rẹ̀ di ìdílé ńlá. Nígbà tí ó bá jáde láyé, tí ó bá sì re ibi àgbà rè, n óo fi ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ jọba, n óo sì jẹ́ kí ìjọba rẹ̀ lágbára. Òun ni yóo kọ́ ilé fún mi, n óo sì rí i dájú pé ìran rẹ̀ ni yóo máa jọba títí laelae. N óo jẹ́ baba fún un, yóo sì jẹ́ ọmọ mi. Bí ó bá ṣẹ̀, n óo bá a wí, n óo sì jẹ ẹ́ níyà, bí baba ti í ṣe sí ọmọ rẹ̀. Ṣugbọn n kò ní káwọ́ ìfẹ́ ńlá mi kúrò lára rẹ̀, bí mo ti ká a kúrò lára Saulu, tí mo sì yọ ọ́ lóyè, kí n tó fi í jọba. Ìran rẹ kò ní parun, arọmọdọmọ rẹ ni yóo sì máa jọba títí ayé, ìjọba rẹ̀ yóo sì wà títí lae.’ ” Natani bá tọ Dafidi lọ, ó sì sọ gbogbo nǹkan tí OLUWA fi hàn án fún un. Dafidi ọba bá wọlé, ó jókòó níwájú OLUWA, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbadura pé, “Ìwọ OLUWA Ọlọrun! Kí ni mo jẹ́, kí ni ilé mi jámọ́ tí o fi gbé mi dé ipò yìí? Sibẹsibẹ, kò jẹ́ nǹkankan lójú rẹ, OLUWA Ọlọrun, o ti ṣèlérí fún èmi iranṣẹ rẹ nípa arọmọdọmọ mi, nípa ọjọ́ iwájú, o sì ti fihàn. Kí ni mo tún lè sọ? O ṣá ti mọ̀ mí, èmi iranṣẹ rẹ, OLUWA Ọlọrun! Nítorí ìlérí ati ìfẹ́ ọkàn rẹ ni o fi ṣe gbogbo nǹkan ńlá wọnyi, kí iranṣẹ rẹ lè mọ̀ nípa wọn. OLUWA Ọlọrun, o tóbi gan-an! Kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn rẹ, nítorí gbogbo ohun tí a ti fi etí wa gbọ́. Kò sí orílẹ̀-èdè mìíràn ní gbogbo ayé, tí ó dàbí Israẹli, tí o yọ kúrò ní oko ẹrú láti fi wọ́n ṣe eniyan rẹ. O ti mú kí òkìkí Israẹli kàn nípa àwọn nǹkan ńláńlá, ati nǹkan ìyanu tí o ti ṣe fún wọn, nípa lílé àwọn eniyan orílẹ̀-èdè mìíràn jáde tàwọn ti oriṣa wọn, bí àwọn eniyan rẹ ti ń tẹ̀síwájú. O ti yan àwọn ọmọ Israẹli fún ara rẹ, láti jẹ́ eniyan rẹ, o sì ti di Ọlọrun wọn títí lae. “Ǹjẹ́ nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun, jẹ́ kí ìlérí tí o ṣe nípa èmi ati arọmọdọmọ mi ṣẹ nígbà gbogbo, sì ṣe ohun tí o ti ṣèlérí pé o óo ṣe. Orúkọ rẹ yóo sì lókìkí títí lae, gbogbo eniyan ni yóo sì máa wí títí lae pé, OLUWA àwọn ọmọ ogun ni Ọlọrun Israẹli. O óo sì mú kí arọmọdọmọ mi wà níwájú rẹ títí laelae. OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli, pẹlu ìgboyà ni mo fi gbadura mi yìí sí ọ, nítorí pé o ti fi gbogbo nǹkan wọnyi han èmi iranṣẹ rẹ, o sì ti ṣèlérí pé o óo sọ ìdílé mi di ìdílé ńlá. “Ǹjẹ́ nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun, ìwọ nìkan ni Ọlọ́run, òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ, o sì ti ṣèlérí ohun rere yìí fún iranṣẹ rẹ. Mò ń bẹ̀bẹ̀ pé kí o bukun arọmọdọmọ mi, kí wọ́n lè máa bá ojurere rẹ pàdé nígbà gbogbo. Ìwọ OLUWA Ọlọrun ni o ṣèlérí yìí, ibukun rẹ yóo sì máa wà lórí arọmọdọmọ mi títí laelae.” Lẹ́yìn náà, Dafidi ọba gbógun ti àwọn ará Filistia, ó ṣẹgun wọn, ó sì gba ìlú Mẹtẹgi-ama lọ́wọ́ wọn. Ó ṣẹgun àwọn ará Moabu bákan náà, ó sì mú kí àwọn tí ó kó lẹ́rú ninu wọn dọ̀bálẹ̀ lórí ilẹ̀ ní ìlà mẹta, ó pa gbogbo àwọn tí wọ́n wà lórí ìlà meji, ó sì dá àwọn tí wọ́n dọ̀bálẹ̀ lórí ìlà kan sí, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Moabu ṣe di ẹrú rẹ̀, tí wọ́n sì ń san owó ìṣákọ́lẹ̀ fún un. Dafidi sì tún ṣẹgun Hadadeseri, ọmọ Rehobu, ọba Soba, bí ó tí ń lọ láti fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ ní ilẹ̀ tí ó wà ní agbègbè odò Yufurate. Ẹẹdẹgbẹsan (1,700) ẹlẹ́ṣin ni Dafidi gbà lọ́wọ́ rẹ̀, ati ọ̀kẹ́ kan àwọn ọmọ ogun tí wọ́n ń fi ẹsẹ̀ rìn. Dafidi dá ẹsẹ̀ àwọn ẹṣin tí ń fa kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ṣugbọn ó dá ọgọrun-un (100) sí ninu wọn. Nígbà tí àwọn ará Siria dé láti Damasku tí wọ́n ran Hadadeseri, ọba Soba lọ́wọ́, Dafidi pa ẹgbaa mọkanla (22,000) ninu àwọn ọmọ ogun wọn. Dafidi bá kọ́ àgọ́ àwọn ọmọ ogun kan sí Aramu, ní Damasku, gbogbo àwọn ará Siria sì ń sin Dafidi, wọ́n sì ń san owó ìṣákọ́lẹ̀ fún un. OLUWA fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibi tí ó lọ. Dafidi gba àwọn apata wúrà tí àwọn ọ̀gágun Hadadeseri fi ń jagun, ó sì kó wọn wá sí Jerusalẹmu. Bákan náà, Dafidi ọba kó ọpọlọpọ idẹ láti Bẹta ati Berotai, ìlú meji ninu àwọn ìlú tí ó wà lábẹ́ ìjọba Hadadeseri. Nígbà tí Toi ọba Hamati gbọ́ pé Dafidi ti ṣẹgun gbogbo àwọn ọmọ ogun Hadadeseri, ó rán Joramu ọmọ rẹ̀ láti kí Dafidi ọba kú oríire, fún ìṣẹ́gun rẹ̀ lórí Hadadeseri, nítorí pé Hadadeseri ti bá Toi jagun ní ọpọlọpọ ìgbà. Joramu mú ọpọlọpọ ẹ̀bùn tí wọ́n fi wúrà ṣe, ati ti fadaka, ati ti idẹ lọ́wọ́ fún Dafidi. Dafidi ọba ya àwọn ẹ̀bùn náà sí mímọ́ fún ìlò ninu ilé OLUWA, pẹlu gbogbo fadaka ati wúrà tí ó rí kó láti gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó ti ṣẹgun; àwọn bíi: àwọn ará Edomu, àwọn ará Moabu, àwọn ará Amoni, àwọn ará Filistia, ati àwọn ará Amaleki; pẹlu ìkógun Hadadeseri, ọba Soba. Dafidi túbọ̀ di olókìkí sí i nígbà tí ó pada dé, láti ibi tí ó ti lọ pa ẹgbaasan-an (18,000) ninu àwọn ará Edomu, ní Àfonífojì Iyọ̀. Ó kọ́ ibùdó àwọn ọmọ ogun káàkiri ilẹ̀ Edomu, gbogbo àwọn ará Edomu sì ń sin Dafidi. OLUWA fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibi tí ó lọ. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ṣe jọba lórí gbogbo Israẹli, ó sì ń ṣe ẹ̀tọ́ ati òdodo sí gbogbo eniyan, nígbà gbogbo. Joabu, ọmọ Seruaya ni balogun rẹ̀, Jehoṣafati, ọmọ Ahiludi ni alákòóso gbogbo àwọn ìwé àkọsílẹ̀ rẹ̀. Sadoku, ọmọ Ahitubu, ati Ahimeleki, ọmọ Abiatari ni alufaa, Seraaya ni akọ̀wé gbọ̀ngàn ìdájọ́ rẹ̀. Bẹnaya, ọmọ Jehoiada ni olórí àwọn Kereti ati àwọn Peleti (tí ń ṣọ́ ààfin), àwọn ọmọ Dafidi ọkunrin ni wọ́n sì jẹ́ alufaa. Ní ọjọ́ kan, Dafidi bèèrè pé, “Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni kù ninu gbogbo ìdílé Saulu tí mo lè ṣoore fún nítorí Jonatani?” Ọkunrin kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Siba, tí ó ti jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ Saulu nígbà ayé rẹ̀. Wọ́n pè é wá fún Dafidi, Dafidi sì bi í pé, “Ṣé ìwọ ni Siba?” Siba dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, oluwa mi, èmi ni.” Ọba tún bi í pé, “Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni kù ninu ìdílé Saulu, tí mo lè fi àánú Ọlọrun hàn, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣèlérí fún Ọlọrun pé n óo ṣe?” Siba dá a lóhùn pé, “Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Jonatani wà láàyè, ṣugbọn arọ ni.” Ọba bi í pé, “Níbo ni ó wà?” Siba dá ọba lóhùn pé, “Ó wà ní ilé Makiri, ọmọ Amieli, ní Lodebari.” Dafidi ọba bá ranṣẹ lọ mú un lati ilé Makiri ọmọ Amieli, ní Lodebari. Nígbà tí Mẹfiboṣẹti, ọmọ Jonatani, tíí ṣe ọmọ ọmọ Saulu dé, ó wólẹ̀ níwájú Dafidi, ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Dafidi pè é, ó ní, “Mẹfiboṣẹti!” ó sì dá a lóhùn pé, “Èmi, iranṣẹ rẹ nìyí.” Dafidi wí fún un pé, “Má bẹ̀rù, oore ni mo fẹ́ ṣe ọ́ nítorí Jonatani baba rẹ. Gbogbo ilẹ̀ tí ó ti jẹ́ ti Saulu baba baba rẹ rí, ni n óo dá pada fún ọ, a óo sì jọ máa jẹun lórí tabili mi nígbà gbogbo.” Mẹfiboṣẹti tún wólẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó ní, “Kí ni èmi iranṣẹ rẹ fi sàn ju òkú ajá lọ, kí ló dé tí o fi ṣe mí ní oore tí ó tó báyìí?” Ọba bá pe Siba, iranṣẹ Saulu, ó wí fún un pé, “Gbogbo ohun tí ó jẹ́ ti Saulu, ọ̀gá rẹ tẹ́lẹ̀, ati ti gbogbo ìdílé rẹ̀, ni n óo dá pada fún Mẹfiboṣẹti ọmọ ọmọ rẹ̀. Ìwọ, àwọn ọmọ rẹ, ati àwọn iranṣẹ rẹ, ni ẹ óo máa ro gbogbo oko Saulu; ẹ ó máa kórè àwọn ohun ọ̀gbìn tí ẹ bá gbìn, kí ọmọ oluwa yín lè ní oúnjẹ tó, ṣugbọn Mẹfiboṣẹti alára, yóo máa wá jẹun lórí tabili mi nígbà gbogbo.” Àwọn ọmọkunrin tí Siba ní nígbà náà jẹ́ mẹẹdogun, àwọn iranṣẹ rẹ̀ sì jẹ́ ogún. Siba dáhùn pé, gbogbo ohun tí ọba pa láṣẹ ni òun yóo ṣe. Mẹfiboṣẹti bá bẹ̀rẹ̀ sí jẹun lórí tabili ọba, gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ọba. Ó ní ọdọmọkunrin kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mika. Gbogbo àwọn ará ilé Siba sì di iranṣẹ Mẹfiboṣẹti. Bẹ́ẹ̀ ni Mẹfiboṣẹti, ẹni tí ẹsẹ̀ rẹ̀ mejeeji ti rọ ṣe bẹ̀rẹ̀ sí gbé Jerusalẹmu, ó sì ń jẹun lọ́dọ̀ ọba nígbà gbogbo. Lẹ́yìn èyí, ni Nahaṣi, ọba Amoni kú, Hanuni, ọmọ rẹ̀ sì gorí oyè. Dafidi ọba wí pé, “N óo ṣe ẹ̀tọ́ fún Hanuni, ọmọ Nahaṣi gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ ti ṣe ẹ̀tọ́ fún mi.” Dafidi bá rán oníṣẹ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti tù ú ninu, nítorí ikú baba rẹ̀. Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ Dafidi dé Amoni, àwọn àgbààgbà ìlú náà wí fún Hanuni ọba wọn pé, “Ṣé o rò pé baba rẹ ni Dafidi bu ọlá fún tóbẹ́ẹ̀, tí ó fi rán àwọn oníṣẹ́ láti wá tù ọ́ ninu? Rárá o! Amí ni ó rán wọn wá ṣe, kí wọ́n lè wo gbogbo ìlú wò, kí ó baà lè ṣẹgun wa.” Hanuni bá ki àwọn oníṣẹ́ Dafidi mọ́lẹ̀, ó fá apá kan irùngbọ̀n ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn, ó gé aṣọ wọn ní déédé ìbàdí, ó sì tì wọ́n jáde. Ìtìjú bá wọn tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wọn kò lè pada sílé. Nígbà tí Dafidi gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn, ó ranṣẹ sí wọn pé kí wọ́n dúró ní Jẹriko títí tí irùngbọ̀n wọn yóo fi hù, kí wọ́n tó máa pada bọ̀. Nígbà tí àwọn ará Amoni rí i pé àwọn ti di ọ̀tá Dafidi, wọ́n ranṣẹ lọ fi owó gba ọ̀kẹ́ kan (20,000) jagunjagun ninu àwọn ará Siria tí wọ́n ń gbé Betirehobu ati Soba. Wọ́n gba ẹgbẹrun (1,000) lọ́dọ̀ ọba Maaka ati ẹgbaafa (12,000) ninu àwọn ará Tobu. Nígbà tí Dafidi gbọ́, ó rán Joabu ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, láti lọ gbógun tì wọ́n. Àwọn ará Amoni jáde sí àwọn ọmọ ogun Israẹli, wọ́n tò sí ẹnubodè wọn ní Raba, tíí ṣe olú ìlú wọn. Gbogbo àwọn ọmọ ogun, ará Siria tí wọ́n wá láti Soba ati Rehobu, ati àwọn ará Tobu ati ti Maaka, àwọn dá dúró ninu pápá. Nígbà tí Joabu rí i pé àwọn ọ̀tá yóo gbógun ti àwọn níwájú ati lẹ́yìn, ó yan àwọn tí wọ́n jẹ́ akikanju jùlọ ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli, ó ní kí wọ́n dojú kọ àwọn ará Siria. Ó sì kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yòókù sábẹ́ ọ̀gágun Abiṣai, tí ó jẹ́ arakunrin rẹ̀, Abiṣai bá fi olukuluku sí ipò rẹ̀, wọ́n dojú kọ àwọn ará Amoni. Joabu wí fún un pé, “Bí o bá rí i pé àwọn ará Siria fẹ́ ṣẹgun mi, wá ràn mí lọ́wọ́. Bí èmi náà bá sì rí i pé àwọn ará Amoni fẹ́ ṣẹgun rẹ, n óo wá ràn ọ́ lọ́wọ́. Múra gírí, jẹ́ kí á fi gbogbo agbára wa jà fún àwọn eniyan wa ati fún ìlú Ọlọrun wa. Kí OLUWA wa ṣe èyí tí ó dára lójú rẹ̀.” Joabu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tẹ̀síwájú láti gbógun ti àwọn ará Siria, àwọn ará Siria sì sá. Nígbà tí àwọn ará Amoni rí i pé àwọn ará Siria ń sá lọ, àwọn náà sá fún Abiṣai, wọ́n sì pada sinu ìlú. Joabu bá pada lẹ́yìn àwọn ará Amoni, ó sì lọ sí Jerusalẹmu. Nígbà tí àwọn ará Siria rí i pé, àwọn ọmọ ogun Israẹli ti ṣẹgun àwọn, wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn jọ. Hadadeseri ọba, bá ranṣẹ sí àwọn ará Siria tí wọ́n wà ní ìhà ìlà oòrùn odò Yufurate, wọ́n bá wá sí Helamu. Ṣobaki tí ó jẹ́ balogun àwọn ọmọ ogun Hadadeseri, ni aṣiwaju wọn. Nígbà tí Dafidi gbọ́, ó kó gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli jọ, ó la odò Jọdani kọjá lọ sí Helamu. Olukuluku àwọn ará Siria dúró ní ipò wọn, wọ́n dojú kọ Dafidi, wọ́n sì bá a jagun. Àwọn ọmọ ogun Israẹli lé àwọn ọmọ ogun Siria pada, Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ pa ẹẹdẹgbẹrin (700) ninu àwọn tí wọ́n gun kẹ̀kẹ́ ogun Siria, ati ọ̀kẹ́ meji (40,000) ninu àwọn ẹlẹ́ṣin wọn. Wọ́n ṣá Ṣobaki tí ó jẹ́ balogun wọn lọ́gbẹ́, ó sì kú sójú ogun. Nígbà tí àwọn ọba tí wọ́n wà lẹ́yìn Hadadeseri rí i pé, àwọn ọmọ Israẹli ti ṣẹgun àwọn, wọ́n bá Israẹli làjà, wọ́n sì ń sìn wọ́n. Láti ìgbà náà ni ẹ̀rù sì ti ń ba àwọn ará Siria láti ran àwọn ará Amoni lọ́wọ́. Ní àkókò ìgbà tí igi ń rúwé, tí ó jẹ́ àkókò tí gbogbo àwọn ọba máa ń lọ sójú ogun, Dafidi rán Joabu ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀ ati àwọn ọmọ ogun Israẹli jáde. Wọ́n ṣẹgun àwọn ará Amoni, wọ́n sì dó ti ìlú Raba, ṣugbọn Dafidi dúró ní Jerusalẹmu. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, nígbà tí Dafidi jí lójú oorun, ó gun orí òrùlé ààfin rẹ̀. Bí ó ti ń rìn káàkiri níbẹ̀, ó rí obinrin kan tí ń wẹ̀, obinrin náà jẹ́ arẹwà gidigidi. Dafidi bá rán oníṣẹ́ lọ, láti wádìí aya ẹni tí obinrin náà í ṣe. Ẹnìkan sì sọ fún un pé Batiṣeba ọmọ Eliamu ni, aya Uraya, ará Hiti. Dafidi bá ranṣẹ lọ pè é. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó bá a lòpọ̀. Batiṣeba sì ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ètò ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ lẹ́yìn tí ó parí nǹkan oṣù rẹ̀ ni. Ó bá pada lọ sí ilé rẹ̀. Nígbà tí ó yá, ó rí i pé òun lóyún, ó sì rán oníṣẹ́, pé kí wọ́n sọ fún Dafidi ọba. Dafidi bá ranṣẹ sí Joabu, pé kí ó fi Uraya ará Hiti ranṣẹ sí òun, Joabu sì fi ranṣẹ sí Dafidi. Nígbà tí Uraya dé, Dafidi bèèrè alaafia Joabu ati ti gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ó bèèrè bí ogun ti ń lọ sí. Lẹ́yìn náà, ó wí fún Uraya pé, “Máa lọ sí ilé rẹ kí o sì sinmi fún ìgbà díẹ̀.” Uraya kúrò lọ́dọ̀ ọba, Dafidi sì di ẹ̀bùn ranṣẹ sí i. Ṣugbọn Uraya kò lọ sí ilé rẹ̀, ó sùn sí ẹnu ọ̀nà ààfin pẹlu àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba tí ń ṣọ́ ààfin. Nígbà tí wọ́n sọ fún Dafidi pé Uraya kò lọ sí ilé rẹ̀, ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “O ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ìrìn àjò dé ni, kí ló dé tí o kò lọ sí ilé rẹ?” Uraya dá a lóhùn pé, “Àwọn ọmọ ogun Israẹli ati ti Juda wà lójú ogun, àpótí ẹ̀rí OLUWA sì wà pẹlu wọn. Joabu balogun mi ati àwọn ọ̀gágun wà lójú ogun, níbi tí wọ́n pàgọ́ sí ní ìta gbangba, ṣé ó yẹ kí n lọ sílé, kí n máa jẹ, kí n máa mu, kí n sì sùn ti aya mi? Níwọ̀n ìgbà tí o wà láyé, tí o sì wà láàyè, n kò jẹ́ dán irú rẹ̀ wò.” Dafidi dá a lóhùn pé, bí ó bá rí bẹ́ẹ̀ dúró níhìn-ín títí di ọ̀la, n óo sì rán ọ pada. Uraya bá dúró ní Jerusalẹmu, ní ọjọ́ náà ati ọjọ́ keji. Dafidi pè é kí ó wá bá òun jẹ oúnjẹ alẹ́ ọjọ́ náà, ó sì fún un ní ọtí mu yó, ṣugbọn Uraya kò lọ sí ilé rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, orí aṣọ òtútù rẹ̀ ni ó sùn, pẹlu àwọn ẹ̀ṣọ́ ninu ilé ìṣọ́ ọba, ní ààfin. Nígbà tí ó di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, Dafidi kọ ìwé kan sí Joabu, ó sì fi rán Uraya. Ìwé náà kà báyìí pé, “Fi Uraya sí iwájú ogun, níbi tí ogun ti gbóná girigiri. Lẹ́yìn náà, kí ẹ dẹ̀yìn lẹ́yìn rẹ̀, kí ogun lè pa á.” Nítorí náà, nígbà tí Joabu dóti ìlú Raba, ó rán Uraya lọ sí ibi tí ó mọ̀ pé àwọn ọ̀tá ti lágbára gidigidi. Àwọn ọmọ ogun àwọn ọ̀tá jáde láti inú ìlú láti bá àwọn ọmọ ogun Joabu jà. Wọ́n pa ninu àwọn ọ̀gágun Dafidi, wọ́n sì pa Uraya ará Hiti náà. Joabu bá ranṣẹ sí Dafidi láti ròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lójú ogun fún un. Ó sọ fún oníṣẹ́ tí ó rán pé, “Bí o bá ti sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lójú ogun fún ọba tán, inú lè bí i, kí ó sì bèèrè lọ́wọ́ rẹ pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi súnmọ́ ìlú náà tóbẹ́ẹ̀ láti bá wọn jà? Ẹ ti gbàgbé pé wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí ta ọfà láti orí ògiri wọn ni? Ẹ ti gbàgbé bí wọ́n ti ṣe pa Abimeleki ọmọ Gideoni? Ṣebí obinrin kan ni ó ju ọlọ ata sílẹ̀ láti orí ògiri ní Tebesi, tí ó sì pa á. Kí ló dé tí ẹ fi súnmọ́ ògiri tóbẹ́ẹ̀?’ Bí ọba bá bèèrè irú ìbéèrè yìí, sọ fún un pé, ‘Wọ́n ti pa Uraya, ọ̀kan ninu àwọn ọ̀gágun rẹ̀ pẹlu.’ ” Oníṣẹ́ náà bá tọ Dafidi lọ, ó sì ròyìn fún un gẹ́gẹ́ bí Joabu ti rán an pé kí ó sọ. Ó ní, “Àwọn ọ̀tá wa lágbára jù wá lọ, wọ́n sì jáde láti inú ìlú wọn láti bá wa jà ninu pápá, ṣugbọn a lé wọn pada títí dé ẹnubodè ìlú wọn. Àwọn tafàtafà bẹ̀rẹ̀ sí ta ọfà sí wa láti orí ògiri wọn, wọ́n sì pa ninu àwọn ọ̀gágun rẹ, wọ́n pa Uraya náà pẹlu.” Dafidi rán oníṣẹ́ náà sí Joabu pé, “Má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí da ọkàn rẹ rú níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé ẹnikẹ́ni kò lè mọ ẹni tí ogun yóo pa. Tún ara mú gidigidi, kí o sì gba ìlú náà.” Nígbà tí Batiṣeba gbọ́ pé wọ́n ti pa ọkọ òun, ó ṣọ̀fọ̀ rẹ̀. Nígbà tí àkókò ọ̀fọ̀ rẹ̀ parí, Dafidi ní kí wọ́n mú un wá sí ààfin, Batiṣeba sì di aya rẹ̀. Ó bí ọmọkunrin kan fún un, ṣugbọn inú OLUWA kò dùn sí ohun tí Dafidi ṣe. OLUWA rán Natani wolii sí Dafidi. Natani bá tọ Dafidi lọ, ó sì sọ fún un pé, “Àwọn ọkunrin meji wà ninu ìlú kan, ọ̀kan jẹ́ ọlọ́rọ̀, ekeji sì jẹ́ talaka. Ọkunrin ọlọ́rọ̀ yìí ní ọpọlọpọ agbo mààlúù, ati agbo aguntan. Ṣugbọn ọkunrin talaka yìí kò ní nǹkankan, àfi ọmọ aguntan kékeré kan tí ó rà, tí ó sì ń tọ́jú títí tí ó fi dàgbà ninu ilé rẹ̀, pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀. Ninu oúnjẹ tí òun pàápàá ń jẹ ni ó ti ń fún un jẹ, igbá tí ọkunrin yìí fi ń mu omi ni ó fi ń bu omi fún ọmọ aguntan rẹ̀ mu. A sì máa gbé e jókòó lórí ẹsẹ̀, bí ẹni pé ọmọ rẹ̀ gan-an ni. Nígbà tí ó di ọjọ́ kan, àlejò dé bá ọkunrin olówó ninu ilé rẹ̀. Ọkunrin yìí kò fẹ́ fọwọ́ kan èyíkéyìí ninu ẹran tirẹ̀ láti pa ṣe àlejò náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹyọ ọmọ aguntan kan tí talaka yìí ní, ni olówó yìí gbà, tí ó sì pa ṣe àlejò.” Nígbà tí Dafidi gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, inú bí i gidigidi sí ọkunrin ọlọ́rọ̀ náà tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi OLUWA Alààyè búra pé ẹni tí ó dán irú rẹ̀ wò, kíkú ni yóo kú. Ó sì níláti san ìlọ́po mẹrin ọmọ aguntan tí ó gbà pada, nítorí nǹkan burúkú tí ó ṣe, ati nítorí pé kò ní ojú àánú. Natani bá dá Dafidi lóhùn pé, “Ìwọ gan-an ni ẹni náà. Ohun tí OLUWA Ọlọrun Israẹli sì ní kí n wí fún ọ nìyí; ó ní, ‘Mo fi ọ́ jọba lórí Israẹli, mo sì gbà ọ́ kúrò lọ́wọ́ Saulu. Mo fún ọ ní ilé oluwa rẹ ati àwọn aya rẹ̀. Mo fi ọ́ jọba lórí Israẹli ati Juda. Ati pé, bí èyí kò bá tó ọ, ǹ bá fún ọ ní ìlọ́po meji rẹ̀. Kí ló dé tí o fi kẹ́gàn ọ̀rọ̀ OLUWA, tí o sì ṣe nǹkan burúkú yìí níwájú rẹ̀. Ìwọ ni o fi Uraya fún ogun pa; tí o jẹ́ kí àwọn Amoni pa á. Lẹ́yìn náà, o gba aya rẹ̀. Nítorí náà, ogun kò ní kúrò ní ìdílé rẹ títí lae; nítorí pé o ti kẹ́gàn mi, o sì ti gba aya Uraya. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Wò ó! N óo jẹ́ kí ẹnìkan ninu ìdílé rẹ ṣe ibi sí ọ. Ojú rẹ ni yóo ṣe tí n óo fi fi àwọn aya rẹ fún ẹlòmíràn, tí yóo sì máa bá wọn lòpọ̀ ní ọ̀sán gangan. Níkọ̀kọ̀ ni o dá ẹ̀ṣẹ̀ yìí, ṣugbọn níwájú gbogbo Israẹli, ní ọ̀sán gangan, ni n óo ṣe ohun tí mò ń sọ yìí.’ ” Dafidi bá dáhùn pé, “Mo ti ṣẹ̀ sí OLUWA.” Natani dá a lóhùn pé, “OLUWA ti dáríjì ọ́, o kò sì ní kú. Ṣugbọn nítorí pé ohun tí o ṣe yìí jẹ́ àfojúdi sí OLUWA, ọmọ tí ó bí fún ọ yóo kú.” Natani bá lọ sí ilé rẹ̀. OLUWA fi àìsàn ṣe ọmọ tí aya Uraya bí fún Dafidi. Dafidi bá ń gbadura sí Ọlọrun pé kí ara ọmọ náà lè yá, ó ń gbààwẹ̀, ó sì ń sùn lórí ilẹ̀ lásán ní alaalẹ́. Àwọn àgbààgbà tí wọ́n wà ninu ilé rẹ̀ rọ̀ ọ́, pé kí ó dìde nílẹ̀, ṣugbọn ó kọ̀, kò sì bá wọn jẹ nǹkankan. Ní ọjọ́ keje, ọmọ náà kú, ẹ̀rù sì ba àwọn iranṣẹ Dafidi láti sọ fún un pé ọmọ ti kú. Wọ́n ní, “Ìgbà tí ọmọ yìí wà láàyè, a bá Dafidi sọ̀rọ̀, kò dá wa lóhùn. Báwo ni a ṣe fẹ́ sọ fún un pé ọmọ ti kú? Ó lè pa ara rẹ̀ lára.” Nígbà tí Dafidi rí i pé wọ́n ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, ó fura pé ọmọ ti kú. Ó bèèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ṣé ọmọ ti kú ni?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ó ti kú.” Dafidi bá dìde kúrò ní ilẹ̀, ó wẹ̀, ó fi òróró pa ara rẹ̀, ó pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó sì lọ sí ilé OLUWA láti jọ́sìn. Lẹ́yìn náà, ó pada sí ilé rẹ̀, ó bèèrè fún oúnjẹ, wọ́n gbé e fún un, ó sì jẹ ẹ́. Àwọn iranṣẹ rẹ̀ bi í pé, “Kabiyesi, ọ̀rọ̀ yìí rú wa lójú, kí ni ohun tí ò ń ṣe yìí? Nígbà tí ọmọ yìí wà láàyè, ò ń gbààwẹ̀, ò ń sọkún nítorí rẹ̀. Ṣugbọn gbàrà tí ó kú tán, o dìde o sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹun!” Dafidi dá wọn lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, nígbà tí ó wà láàyè, mo gbààwẹ̀, mo sì sọkún, pé bóyá OLUWA yóo ṣàánú mi, kí ó má kú. Ṣugbọn nisinsinyii, ó ti kú, kí ni n óo tún máa gbààwẹ̀ sí? Ṣé mo lè jí i dìde ni? Èmi ni n óo tọ̀ ọ́ lọ, kò tún lè pada tọ̀ mí wá mọ́.” Dafidi bá tu Batiṣeba, aya rẹ̀ ninu, ó bá a lòpọ̀, ó sì bí ọmọkunrin kan fún un. Dafidi sọ ọmọ yìí ní Solomoni. OLUWA fẹ́ràn ọmọ náà, ó sì rán Natani wolii pé kí ó sọ ọmọ náà ní Jedidaya, nítorí pé, OLUWA fẹ́ràn rẹ̀. Ní gbogbo àkókò yìí, Joabu wà níbi tí ó ti gbógun ti Raba, olú ìlú àwọn ará Amoni, ó sì gba ìlú ọba wọn. Ó ranṣẹ sí Dafidi láti ròyìn fún un pé, “Mo ti gbógun ti Raba, mo sì ti gba ìlú tí orísun omi wọn wà, kó àwọn ọmọ ogun yòókù jọ, kí o kọlu ìlú náà, kí o sì gbà á fúnra rẹ. N kò fẹ́ gba ìlú náà kí ògo gbígbà rẹ̀ má baà jẹ́ tèmi.” Dafidi bá kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ, ó lọ sí Raba, ó gbógun tì í, ó sì ṣẹgun rẹ̀. Dafidi ṣí adé wúrà orí ọba wọn, adé náà wọ̀n tó ìwọ̀n talẹnti wúrà kan, ó sì ní òkúta olówó iyebíye kan lára, ó sì fi dé orí ara rẹ̀. Dafidi kó ọpọlọpọ àwọn ìkógun mìíràn ninu ìlú náà. Ó bẹ̀rẹ̀ sí kó gbogbo àwọn ará ìlú náà ṣiṣẹ́. Àwọn kan ń lo ayùn, àwọn mìíràn ń lo ọkọ́ onírin, ati àáké onírin, àwọn mìíràn sì ń gé bulọọku, wọ́n ń sun ún. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe sí àwọn ará ìlú Amoni yòókù. Lẹ́yìn náà, òun ati àwọn eniyan rẹ̀ pada sí Jerusalẹmu. Absalomu ọmọ Dafidi ní arabinrin kan tí ó jẹ́ arẹwà, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tamari. Dafidi tún ní ọmọkunrin mìíràn tí ń jẹ́ Amnoni. Amnoni yìí fẹ́ràn Tamari lọpọlọpọ. Amnoni fẹ́ràn rẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó di àìsàn sí i lára. Wundia ni Tamari, kò tíì mọ ọkunrin rí; nítorí náà ó dàbí ẹni pé kò ṣeéṣe fún Amnoni láti bá a ṣe nǹkankan. Ṣugbọn Amnoni ní ọ̀rẹ́ kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jonadabu, ọmọ Ṣimea, ọ̀kan ninu àwọn arakunrin Dafidi. Jonadabu yìí jẹ́ alárèékérekè eniyan. Ní ọjọ́ kan, ó bèèrè lọ́wọ́ Amnoni pé, “Ṣebí ọmọ ọba ni ọ́, kí ló dé tí ò ń rù lojoojumọ? Sọ fún mi.” Amnoni dá a lóhùn pé, “Ìfẹ́ Tamari, àbúrò Absalomu, arakunrin mi, ni ó wọ̀ mí lọ́kàn tóbẹ́ẹ̀.” Jonadabu dáhùn, ó ní, “Lọ dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ, kí o sì ṣe bí ẹni pé ara rẹ kò yá. Nígbà tí baba rẹ bá wá bẹ̀ ọ́ wò, wí fún un pé, kí ó jọ̀wọ́ kí ó jẹ́ kí Tamari arabinrin rẹ wá fún ọ ní oúnjẹ. Sọ fún un pé, o fẹ́ kí ó wá se oúnjẹ náà lọ́dọ̀ rẹ níbi tí o ti lè máa rí i, kí ó sì fi ọwọ́ ara rẹ̀ gbé e fún ọ.” Amnoni bá dùbúlẹ̀, ó ṣe bí ẹni tí ó ń ṣàìsàn. Nígbà tí Dafidi ọba lọ bẹ̀ ẹ́ wò, Amnoni wí fún un pé, “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí Tamari, arabinrin mi, wá ṣe àkàrà díẹ̀ lọ́dọ̀ mi níhìn-ín, níbi tí mo ti lè máa rí i, kí ó sì gbé e wá fún mi.” Dafidi bá ranṣẹ pe Tamari ninu ààfin, ó ní kí ó lọ sinu ilé Amnoni, kí ó lọ tọ́jú oúnjẹ fún un. Tamari lọ, ó bá Amnoni lórí ibùsùn níbi tí ó dùbúlẹ̀ sí. Ó bu ìyẹ̀fun díẹ̀, ó pò ó, ó gé e ní ìwọ̀n àkàrà bíi mélòó kan, níbi tí Amnoni ti lè máa rí i. Lẹ́yìn náà, ó gbé e sórí iná títí tí ó fi jinná, ó sì dà á sinu àwo kan, ó gbé e fún un. Ṣugbọn Amnoni kọ̀, kò jẹ ẹ́, ó ní kí ó sọ fún gbogbo àwọn tí wọ́n wà ninu ilé kí wọ́n jáde, gbogbo wọn bá jáde. Amnoni bá sọ fún un pé, “Gbé e tọ̀ mí wá ninu yàrá mi, kí o sì gbé e kalẹ̀ níwájú mi.” Tamari bá gbé àkàrà náà, ó sì tọ Amnoni lọ láti gbé e kalẹ̀ níwájú rẹ̀ ninu yàrá. Bí ó ti ń gbé e fún un, ni Amnoni gbá a mú, ó wí fún un pé, “Wá, mo fẹ́ bá ọ lòpọ̀.” Tamari dáhùn pé, “Rárá, má fi ipá mú mi, nítorí ẹnìkan kò gbọdọ̀ dán irú rẹ̀ wò ní Israẹli, má hùwà òmùgọ̀; níbo ni mo fẹ́ fi ojú sí láàrin gbogbo eniyan? Ohun ìtìjú patapata ni yóo sì jẹ́ fún ìwọ náà ní Israẹli. Jọ̀wọ́, bá ọba sọ̀rọ̀, mo mọ̀ dájúdájú pé yóo fi mí fún ọ.” Ṣugbọn Amnoni kọ̀, kò gbọ́ ohun tí Tamari sọ fún un. Nígbà tí ó sì jẹ́ pé Amnoni lágbára jù ú lọ, ó fi tipátipá bá a lòpọ̀. Lẹ́yìn náà, Amnoni kórìíra rẹ̀ gidigidi. Ìkórìíra náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó tún wá ju bí ó ti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ lọ. Ó ní kí ó bọ́ sóde, kí ó máa lọ. Tamari dá a lóhùn pé, “Rárá, arakunrin mi, lílé tí ò ń lé mi jáde yìí burú ju ipá tí o fi bá mi lòpọ̀ lọ.” Ṣugbọn Amnoni kọ̀, kò gbọ́ tirẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, Amnoni pe iranṣẹ rẹ̀ kan, ó wí fún un pé, “Mú obinrin yìí jáde kúrò níwájú mi, tì í sóde, kí o sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ ọn.” Iranṣẹ náà bá ti Tamari jáde, ó sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ ọn. Aṣọ àwọ̀kanlẹ̀ alápá gígùn, irú èyí tí àwọn ọmọ ọba, obinrin, tí kò tíì wọlé ọkọ máa ń wọ̀, ni Tamari wọ̀. Tamari bá ku eérú sí orí, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó káwọ́ lórí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọkún bí ó ti ń lọ. Nígbà tí Absalomu, ẹ̀gbọ́n Tamari, rí i, ó bi í léèrè pé, “Ṣé Amnoni bá ọ lòpọ̀ ni? Jọ̀wọ́, arabinrin mi, gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn, ọmọ baba kan náà ni ẹ̀yin mejeeji, nítorí náà, má sọ fún ẹnikẹ́ni.” Tamari bá ń gbé ilé Absalomu. Òun nìkan ni ó dá wà, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ pupọ. Nígbà tí Dafidi ọba gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, inú bí i gidi. Absalomu kórìíra Amnoni gan-an nítorí pé ó fi ipá bá Tamari, àbúrò rẹ̀, lòpọ̀, ṣugbọn kò bá a sọ nǹkankan; ìbáà ṣe rere ìbáà sì ṣe burúkú. Lẹ́yìn ọdún meji tí nǹkan yìí ṣẹlẹ̀, Absalomu lọ rẹ́ irun aguntan rẹ̀ ní Baali Hasori, lẹ́bàá ìlú Efuraimu, ó sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba patapata lọkunrin sibẹ. Ó lọ sí ọ̀dọ̀ Dafidi ọba, ó wí fún un pé, “Kabiyesi, iranṣẹ rẹ ń rẹ́ irun aguntan rẹ̀, mo sì fẹ́ kí kabiyesi ati gbogbo àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ wá síbi àjọ̀dún náà.” Ọba ní, “Rárá, ọmọ mi, bí gbogbo wa bá lọ, wahala náà yóo pọ̀jù fún ọ.” Absalomu rọ ọba títí, ṣugbọn ó kọ̀ jálẹ̀. Ọba bá súre fún un, ó ní kí ó máa lọ. Absalomu dáhùn pé, “Ó dára, bí o kò bá lè lọ, ṣé o óo jẹ́ kí Amnoni arakunrin mi lọ?” Ọba bá bèèrè pé, “Nítorí kí ni yóo ṣe ba yín lọ?” Ṣugbọn Absalomu rọ Dafidi títí tí ó fi gbà pé kí Amnoni ati àwọn ọmọ ọba yòókù lọkunrin bá a lọ. Absalomu sì se àsè rẹpẹtẹ, bí ẹni pé ọba ni ó fẹ́ ṣe lálejò. Absalomu wí fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ẹ máa kíyèsí Amnoni, nígbà tí ó bá mu ọtí yó, bí mo bá ti fun yín ní àṣẹ pé kí ẹ pa á, pípa ni kí ẹ pa á, ẹ má bẹ̀rù; èmi ni mo ran yín. Ẹ mú ọkàn gírí kí ẹ sì ṣe bí akikanju.” Àwọn iranṣẹ náà bá tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀, wọ́n sì pa Amnoni. Gbogbo àwọn ọmọ Dafidi yòókù bá gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, wọ́n sì sá lọ. Nígbà tí wọn ń sá bọ̀ wálé, àwọn kan wá sọ fún Dafidi pé, “Absalomu ti pa gbogbo àwọn ọmọ rẹ, ati pé kò ṣẹ́ku ẹyọ ẹnìkan.” Ọba dìde, ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn, ó sì sùn sórí ilẹ̀ lásán, àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ fa aṣọ tiwọn náà ya. Ṣugbọn Jonadabu, ọmọ Ṣimea, arakunrin Dafidi, wí fún ọba pé, “Kabiyesi, ẹnikẹ́ni kò pa gbogbo àwọn ọmọ rẹ. Amnoni nìkan ni Absalomu pàṣẹ pé kí wọ́n pa. Láti ìgbà tí Amnoni ti fi ipá bá Tamari, arabinrin rẹ̀ lòpọ̀, ni ó ti pinnu láti ṣe ohun tí ó ṣe yìí. Nítorí náà, kí oluwa mi má gba ìròyìn tí wọ́n mú wá gbọ́, pé gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ ni wọ́n ti kú. Amnoni nìkan ni wọ́n pa.” Absalomu sá lọ ní àkókò yìí. Kò pẹ́ rárá, lẹ́yìn náà, ọmọ ogun tí ń ṣọ́ ọ̀nà tí ó wọ ìlú rí ogunlọ́gọ̀ eniyan, wọ́n ń bọ̀ láti ọ̀nà Horonaimu, lẹ́bàá òkè. Jonadabu bá sọ fún ọba pé, “Àwọn ọmọ oluwa mi ni wọ́n ń bọ̀ yìí, gẹ́gẹ́ bí mo ti wí.” Ó fẹ́rẹ̀ má tíì dákẹ́ ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, tí àwọn ọmọ Dafidi fi wọlé, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọkún, Dafidi ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ náà sì sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn. Ṣugbọn Absalomu sá lọ sọ́dọ̀ Talimai, ọmọ Amihudu, ọba Geṣuri, Dafidi sì ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ lojoojumọ. Absalomu wà ní Geṣuri níbi tí ó sá lọ fún ọdún mẹta. Nígbà tí ó yá tí Dafidi gbé ìbànújẹ́ ikú Amnoni ọmọ rẹ̀ kúrò lára, ọkàn Absalomu ọmọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fà á. Joabu, ọmọ Seruaya, ṣe akiyesi pé ọkàn Absalomu ń fa Dafidi pupọ. Nítorí náà, ó ranṣẹ sí ọlọ́gbọ́n obinrin kan, tí ń gbé Tekoa. Nígbà tí obinrin yìí dé, Joabu wí fún un pé, “Ṣe bí ẹni pé o wà ninu ọ̀fọ̀, wọ aṣọ ọ̀fọ̀, má fi òróró para, kí o sì fi irun rẹ sílẹ̀ játijàti. Ṣe bí ẹni tí ó ti wà ninu ọ̀fọ̀ fún ọjọ́ pípẹ́; kí o lọ sọ́dọ̀ ọba, kí o sì sọ ohun tí n óo sọ fún ọ yìí fún un.” Joabu bá kọ́ ọ ní ohun tí yóo wí. Obinrin ará Tekoa náà bá tọ ọba lọ, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó wí fún un báyìí pé, “Kabiyesi, gbà mí.” Ọba bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni o fẹ́?” Ó dá ọba lóhùn pé, “Kabiyesi, opó ni mí, ọkọ mi ti kú. Ọmọkunrin meji ni mo bí. Ní ọjọ́ kan, àwọn mejeeji ń bá ara wọn jà ninu pápá, kò sì sí ẹnikẹ́ni nítòsí láti là wọ́n, ni ọ̀kan ninu wọn bá lu ekeji rẹ̀ pa. Nisinsinyii, kabiyesi, gbogbo àwọn eniyan mi ni wọ́n ti kẹ̀yìn sí mi. Wọ́n ní dandan kí ń fa ọmọ mi kan yòókù kalẹ̀ fún àwọn, kí wọ́n lè pa á nítorí arakunrin rẹ̀ tí ó pa. Bí mo bá gbà fún wọn, kò ní sí ẹni tí yóo jogún ọkọ mi, wọn yóo já ìrètí mi kan tí ó kù kulẹ̀, kò sì ní sí ọmọkunrin tí yóo gbé orúkọ ọkọ mi ró, tí orúkọ náà kò fi ní parun.” Ọba dá a lóhùn pé, “Máa pada lọ sí ilé rẹ, n óo mójú tó ọ̀rọ̀ náà.” Obinrin náà wí fún ọba pé, “Kabiyesi, gbogbo ohun tí o bá ṣe nípa ọ̀rọ̀ yìí, èmi ati ìdílé mi ni a ni ẹ̀bi rẹ̀, ẹ̀bi rẹ̀ kò kan kabiyesi ati ìdílé rẹ̀ rárá.” Ọba dá a lóhùn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá tún halẹ̀ mọ́ ọ, mú olúwarẹ̀ wá sọ́dọ̀ mi, kò sì ní dé ọ̀dọ̀ rẹ mọ́ laelae.” Obinrin yìí tún wí fún ọba pé, “Kabiyesi, jọ̀wọ́, gbadura sí OLUWA Ọlọrun rẹ kí ẹni tí ó fẹ́ gbẹ̀san ikú ọmọ mi kinni má baà pa ọmọ mi keji.” Dafidi ọba bá dáhùn pé, “Mo ṣèlérí fún ọ, ní orúkọ OLUWA Ọlọrun alààyè, pé, ẹnikẹ́ni kò ní ṣe ọmọ rẹ ní ohunkohun.” Obinrin yìí bá tún dáhùn pé, “Kabiyesi, jọ̀wọ́, jẹ́ kí n sọ gbolohun kan yìí sí i.” Ọba dáhùn pé, “Ó dára, mò ń gbọ́.” Obinrin náà wí pé, “Kí ló dé tí o fi ṣe ohun tí ó burú yìí sí àwọn eniyan Ọlọrun? Ọ̀rọ̀ tí o sọ tán nisinsinyii, ara rẹ gan-an ni o fi dá lẹ́bi, nítorí pé, o kò jẹ́ kí ọmọ rẹ pada wá sílé láti ibi tí ó sá lọ? Dájúdájú, gbogbo wa ni a óo kú. A dàbí omi tí ó dà sílẹ̀, tí ẹnikẹ́ni kò sì lè kójọ mọ́. Ẹni tí ó bá ti kú, Ọlọrun pàápàá kì í tún gbé e dìde mọ́, ṣugbọn kabiyesi lè wá ọ̀nà, láti fi mú ẹni tí ó bá sá jáde kúrò ní ìlú pada wálé. Kabiyesi, ìdí tí mo fi kó ọ̀rọ̀ mi tọ̀ ọ́ wá ni pé, àwọn eniyan ń dẹ́rùbà mí, èyí ni ó mú kí n rò ninu ara mi pé, n óo wá bá ọ sọ̀rọ̀, mo sì ní ìrètí pé, kabiyesi yóo ṣe ohun tí mo wá bẹ̀bẹ̀ pé kí ó bá mi ṣe. Mo mọ̀ pé ọba yóo fetí sílẹ̀ láti gbọ́ tèmi, yóo sì gbà mí kalẹ̀ lọ́wọ́ ẹni tí ó fẹ́ pa èmi ati ọmọ mi, tí ó sì fẹ́ pa wá run kúrò lórí ilẹ̀ tí Ọlọrun fún àwọn eniyan rẹ̀. Mo sì ti mọ̀ lọ́kàn ara mi pé, ọ̀rọ̀ tí kabiyesi bá sọ fún mi yóo fi mí lọ́kàn balẹ̀ nítorí pé, ọba dàbí angẹli Ọlọrun tí ó mọ ìyàtọ̀ láàrin ire ati ibi. OLUWA Ọlọrun rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀.” Ọba dá obinrin náà lóhùn pé, “Ọ̀rọ̀ kan ni mo fẹ́ bèèrè lọ́wọ́ rẹ, mo sì fẹ́ kí o sọ òtítọ́ rẹ̀ fún mi.” Obinrin náà dáhùn pé, “Kabiyesi, bèèrè ohunkohun tí o bá fẹ́.” Ọba bá bí i pé, “Ṣé Joabu ni ó rán ọ ní gbogbo iṣẹ́ tí o wá jẹ́ yìí, àbí òun kọ?” Obinrin náà dáhùn pé, “Kabiyesi, bí o ti bèèrè ìbéèrè yìí kò jẹ́ kí n mọ̀ bí mo ti lè yí ẹnu pada rárá. Òtítọ́ ni, Joabu ni ó kọ́ mi ní gbogbo ohun tí mo sọ, ati gbogbo bí mo ti ṣe. Ṣugbọn, òun náà fẹ́ tún nǹkan ṣe, ni ó fi ṣe ohun tí ó ṣe. Ṣugbọn kabiyesi ní ọgbọ́n bí angẹli Ọlọ́run, láti mọ ohun gbogbo lórí ilẹ̀ ayé.” Nígbà náà ni ọba sọ fún Joabu pé, “Mo ti pinnu láti ṣe ohun tí o fẹ́ kí n ṣe. Lọ, kí o sì mú Absalomu, ọmọ mi, pada wá.” Joabu bá wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ ọba, ó ní, “Kabiyesi, nisinsinyii ni èmi iranṣẹ rẹ mọ̀ pé mo ti bá ojurere rẹ pàdé, nítorí pé o ṣe ohun tí mo fẹ́.” Joabu bá gbéra, ó lọ sí Geṣuri, ó sì mú Absalomu pada wá sí Jerusalẹmu. Ṣugbọn ọba pàṣẹ pé kí Absalomu máa gbé ilé rẹ̀, nítorí pé òun kò fẹ́ rí i sójú. Nítorí náà, inú ilé Absalomu ni ó ń gbé, kò sì dé ọ̀dọ̀ ọba rárá. Kò sí ẹyọ ẹnìkan ní gbogbo Israẹli tí òkìkí ẹwà rẹ̀ kàn bí ti Absalomu. Kò sí àbùkù kankan rárá lára rẹ̀ bí ti í wù kó mọ, láti orí títí dé àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀. Ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún ni í máa ń gé irun orí rẹ̀, nígbà tí ó bá kún, tí ó sì gùn ju bí ó ti yẹ lọ. Tí wọ́n bá fi ìwọ̀n ọba wọn èyí tí wọ́n bá gé lára irun rẹ̀, a máa tó igba ṣekeli. Absalomu bí ọmọkunrin mẹta ati ọmọbinrin kan. Tamari ni orúkọ ọmọbinrin yìí, ó sì jẹ́ arẹwà. Ọdún meji ni Absalomu fi gbé Jerusalẹmu láì fi ojú kan ọba. Ní ọjọ́ kan, ó ranṣẹ sí Joabu, pé kí ó wá mú òun lọ sọ́dọ̀ ọba, ṣugbọn Joabu kọ̀, kò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Absalomu ranṣẹ pe Joabu lẹẹkeji, Joabu sì tún kọ̀, kò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Absalomu bá pe àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Oko Joabu wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ tèmi, ó sì gbin ọkà baali sinu rẹ̀, ẹ lọ fi iná sí oko náà.” Wọ́n bá lọ, wọ́n sì ti iná bọ oko Joabu. Nígbà náà ni Joabu lọ sí ilé Absalomu, ó bi í pé, “Kí ló dé tí àwọn iranṣẹ rẹ fi ti iná bọ oko mi?” Absalomu dáhùn pé, “Nítorí pé mo ranṣẹ pè ọ́, pé kí o wá, kí n lè rán ọ lọ bèèrè lọ́wọ́ ọba pé, ‘Kí ni mo kúrò ní Geṣuri tí mo sì wá síhìn-ín fún? Ìbá sàn kí n kúkú wà lọ́hùn-ún.’ Mo fẹ́ kí o ṣe ètò kí n lè fi ojú kan ọba, bí ó bá sì jẹ́ pé mo jẹ̀bi, kí ó pa mí.” Joabu bá tọ Dafidi ọba lọ, ó sì sọ ohun tí Absalomu wí fún un. Ọba ranṣẹ pe Absalomu, ó sì wá sọ́dọ̀ ọba. Ó wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀, ọba bá fi ẹnu kò ó ní ẹnu. Lẹ́yìn èyí, Absalomu wá kẹ̀kẹ́ ogun kan, ati àwọn ẹṣin, ati aadọta ọkunrin tí wọn yóo máa sáré níwájú rẹ̀. A máa jí ní òwúrọ̀ kutukutu, a sì dúró ní ẹ̀bá ọ̀nà, ní ẹnu ibodè ìlú. Nígbàkúùgbà tí ẹnikẹ́ni bá ń mú ẹjọ́ bọ̀ wá sọ́dọ̀ ọba, Absalomu á pe olúwarẹ̀ sọ́dọ̀, á bi í pé, “Níbo ni o ti wá?” Lẹ́yìn ìgbà tí ẹni náà bá sọ inú ẹ̀yà tí òun ti wá fún Absalomu tán, Absalomu á wí fún un pé, “Wò ó, ẹjọ́ rẹ tọ́, o sì jàre, ṣugbọn ọba kò yan ẹnikẹ́ni gẹ́gẹ́ bí aṣojú rẹ̀, láti máa gbọ́ irú ẹjọ́ báyìí.” Absalomu á tún wá fi kún un pé, “A! Bí wọ́n bá fi mí ṣe adájọ́ ní ilẹ̀ yìí ni, bí ẹnikẹ́ni bá ní èdè-àìyedè kan pẹlu ẹlòmíràn, tabi tí ẹnìkan bá fẹ́ gba ohun tíí ṣe ẹ̀tọ́ rẹ̀, wọn ìbá máa tọ̀ mí wá, ǹ bá sì máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́ fún wọn.” Bí ẹnikẹ́ni bá súnmọ́ Absalomu láti wólẹ̀, kí ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, Absalomu á tètè na ọwọ́ sí i, á gbá a mú, a sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu. Bẹ́ẹ̀ ni Absalomu máa ń ṣe sí gbogbo àwọn eniyan Israẹli, tí wọ́n bá kó ẹjọ́ wá sọ́dọ̀ ọba. Nítorí bí ó ti ń ṣe yìí, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n fẹ́ràn rẹ̀. Ní ìparí ọdún kẹrin, Absalomu tọ Dafidi lọ, ó ní, “Kabiyesi, fún mi láàyè kí n lọ sí Heburoni. Mo fẹ́ lọ san ẹ̀jẹ́ kan tí mo jẹ́ fún OLUWA. Nígbà tí mo fi wà ní Geṣuri, ní ilẹ̀ Siria, mo jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLUWA, pé bí ó bá mú mi pada sí Jerusalẹmu, n óo lọ sìn ín ní Heburoni.” Ọba bá dá a lóhùn pé kí ó máa lọ ní alaafia, Absalomu bá dìde ó lọ sí Heburoni. Ṣugbọn Absalomu rán iṣẹ́ àṣírí sí gbogbo ẹ̀yà Israẹli, ó ní, “Tí ẹ bá gbọ́ tí wọ́n fọn fèrè, kí ẹ sọ pé, ‘Absalomu ti di ọba ní Heburoni.’ ” Igba ọkunrin ni Absalomu pè, tí wọ́n sì bá a lọ láti Jerusalẹmu. Wọn kò ní èrò ibi lọ́kàn, ní tiwọn, wọn kò sì mọ ohun tí ó wà lọ́kàn Absalomu. Nígbà tí Absalomu ń rúbọ lọ́wọ́, ó ranṣẹ sí ìlú Gilo láti lọ pe Ahitofeli ará Gilo, ọ̀kan ninu àwọn olùdámọ̀ràn Dafidi ọba. Ọ̀tẹ̀ tí Absalomu ń dì ń gbilẹ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ náà ń pọ̀ sí i. Oníṣẹ́ kan wá ròyìn fún Dafidi pé, “Ọkàn gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ti ṣí sí ọ̀dọ̀ Absalomu.” Dafidi bá sọ fún gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀, tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ní Jerusalẹmu pé, “A gbọdọ̀ sá lọ lẹsẹkẹsẹ, bí a kò bá fẹ́ bọ́ sọ́wọ́ Absalomu. Ẹ ṣe gírí, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, yóo bá wa, yóo ṣẹgun wa, yóo sì pa ìlú yìí run.” Àwọn iranṣẹ rẹ̀ dáhùn pé, “Kabiyesi, ohunkohun tí o bá wí ni a óo ṣe.” Ọba bá jáde kúrò ní ìlú, gbogbo ìdílé rẹ̀, ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Ṣugbọn ọba fi mẹ́wàá ninu àwọn obinrin rẹ̀ sílẹ̀ láti máa bojútó ààfin. Bí ọba ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ ti ń jáde kúrò ní ìlú, wọ́n dúró níbi ilé tí ó wà ní ìpẹ̀kun ìlú. Gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀ sì ń tò kọjá níwájú rẹ̀; àwọn ẹgbẹta (600) ọmọ ogun tí wọ́n tẹ̀lé e láti Gati náà tò kọjá níwájú rẹ̀. Ọba bá kọjú sí Itai ará Gati, ó sì bi í pé, “Kí ló dé tí o fi ń bá wa lọ? Pada, kí o lọ dúró ti ọba, àlejò ni ọ́, sísá ni o sá kúrò ní ìlú rẹ wá síhìn-ín. Kò sì tíì pẹ́ pupọ tí o dé, kí ló dé tí o fi fẹ́ máa bá mi káàkiri ninu ìrìnkèrindò mi? Èmi gan-an nìyí, n kò tíì mọ ibi tí mò ń lọ. Pada kí àwọn ará ìlú rẹ gbogbo sì máa bá ọ lọ. OLUWA yóo fẹ́ràn ìwọ náà, yóo sì dúró tì ọ́.” Ṣugbọn Itai dáhùn pé, “Kabiyesi, mo fi OLUWA búra, bí ẹ̀mí oluwa mi ọba tí ń bẹ láàyè, pé, ibikíbi tí o bá ń lọ ni n óo máa bá ọ lọ, kì báà tilẹ̀ já sí ikú.” Dafidi dáhùn, ó ní, “Kò burú.” Itai ati àwọn eniyan rẹ̀, ati àwọn ọmọ kéékèèké, tò kọjá níwájú ọba. Gbogbo ìlú bú sẹ́kún bí àwọn eniyan náà ti ń lọ. Ọba rékọjá odò Kidironi, àwọn eniyan rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Gbogbo wọ́n jọ ń lọ sí ọ̀nà apá ijù. Sadoku, alufaa, wà láàrin wọn, àwọn ọmọ Lefi sì wà pẹlu rẹ̀, wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí lọ́wọ́. Wọ́n gbé e kalẹ̀ títí tí gbogbo àwọn eniyan náà fi jáde kúrò ní ìlú. Abiatari, alufaa náà wà láàrin wọn. Ọba wí fún Sadoku pé, “Gbé Àpótí Ẹ̀rí náà pada sí ìlú. Bí inú OLUWA bá dùn sí mi, bí mo bá bá ojurere OLUWA pàdé, yóo mú mi pada, n óo tún fi ojú kan Àpótí Ẹ̀rí náà ati ilé OLUWA. Ṣugbọn bí inú rẹ̀ kò bá dùn sí mi, kí ó ṣe mí bí ó bá ti tọ́ ní ojú rẹ̀.” Ó tún fi kún un fún Sadoku pé, “Wò ó! Ìwọ ati Abiatari, ẹ pada sí ìlú ní alaafia, mú Ahimaasi, ọmọ rẹ, ati Jonatani ọmọ Abiatari lọ́wọ́. N óo dúró ní ibi tí wọ́n ń gbà la odò kọjá ní ijù níhìn-ín, títí tí n óo fi rí oníṣẹ́ rẹ.” Sadoku ati Abiatari bá gbé àpótí ẹ̀rí pada sí Jerusalẹmu, wọ́n sì wà níbẹ̀. Ṣugbọn Dafidi gun gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè olifi lọ, láì wọ bàtà, ó ń sọkún bí ó ti ń lọ, ó sì fi aṣọ bo orí rẹ̀ láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn. Gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, tí wọ́n ń bá a lọ náà fi aṣọ bo orí wọn, wọ́n sì ń sọkún bí wọ́n ti ń lọ. Nígbà tí wọ́n sọ fún Dafidi pé, Ahitofeli ti darapọ̀ mọ́ ọ̀tẹ̀ tí Absalomu ń dì, Dafidi gbadura sí OLUWA, ó ní, “Jọ̀wọ́, OLUWA, yí gbogbo ìmọ̀ràn tí Ahitofeli bá fún Absalomu pada sí asán.” Nígbà tí Dafidi gun òkè náà dé orí, níbi tí wọ́n ti máa ń rúbọ sí Ọlọ́run, Huṣai, ará Ariki, wá pàdé rẹ̀ pẹlu aṣọ rẹ̀ tí ó ti ya, ó sì ti ku eruku sí orí rẹ̀. Dafidi wí fún un pé, “Bí o bá bá mi lọ, ìdíwọ́ ni o óo jẹ́ fún mi. Bí o bá pada sí ìlú, tí o sì sọ fún Absalomu, ọba, pé o ti ṣetán láti sìn ín pẹlu ẹ̀mí òtítọ́, gẹ́gẹ́ bí o ti sin èmi baba rẹ̀, nígbà náà ni o óo ní anfaani láti bá mi yí ìmọ̀ràn Ahitofeli po. Ṣebí Sadoku ati Abiatari, àwọn alufaa mejeeji wà níbẹ̀, gbogbo ohun tí o bá ti gbọ́ ninu ààfin ọba ni kí o máa sọ fún wọn. Àwọn ọmọ wọn mejeeji, Ahimaasi ati Jonatani wà lọ́dọ̀ wọn. Gbogbo ohun tí ẹ bá gbọ́, kí ẹ máa rán wọn sí mi.” Huṣai bá pada, ó dé Jerusalẹmu bí Absalomu tí ń wọ ìlú bọ̀ gẹ́lẹ́. Ní gẹ́rẹ́ tí Dafidi kọjá góńgó orí òkè náà, Siba, iranṣẹ Mẹfiboṣẹti pàdé rẹ̀, ó ń da àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bíi mélòó kan bọ̀ tí ó di igba (200) burẹdi rù, pẹlu ọgọrun-un ṣiiri èso resini, ati ọgọrun-un ṣiiri èso tútù mìíràn ati àpò aláwọ kan tí ó kún fún ọtí waini. Dafidi ọba bi í pé, “Kí ni o fẹ́ fi gbogbo nǹkan wọnyi ṣe?” Siba dá a lóhùn pé, “Mo mú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọnyi wá kí àwọn ìdílé Kabiyesi lè rí nǹkan gùn, mo mú burẹdi, ati èso wọnyi wá kí àwọn ọdọmọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ lè rí nǹkan jẹ; ati ọtí waini, kí àwọn tí àárẹ̀ bá mú ninu aṣálẹ̀ lè rí nǹkan mu.” Ọba tún bi í pé, “Níbo ni Mẹfiboṣẹti, ọmọ ọmọ Saulu, ọ̀gá rẹ wà?” Siba dá a lóhùn pé, “Mẹfiboṣẹti dúró sí Jerusalẹmu; nítorí ó dá a lójú pé, nisinsinyii ni àwọn ọmọ Israẹli yóo dá ìjọba Saulu baba-baba rẹ̀ pada fún un.” Ọba bá sọ fún Siba pé, “Gbogbo ohun tí ó jẹ́ ti Mẹfiboṣẹti di tìrẹ láti ìsinsìnyìí lọ.” Siba sọ fún ọba pé, “Kabiyesi, mo júbà, jọ̀wọ́, jẹ́ kí n máa bá ojurere rẹ pàdé nígbà gbogbo.” Nígbà tí Dafidi ọba dé Bahurimu, ọkunrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣimei, ọmọ Gera, láti inú ìdílé Saulu, jáde sí i, bí ó sì ti ń bọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó ń ṣépè lemọ́lemọ́. Ó ń sọ òkúta lu Dafidi ati gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn eniyan ńláńlá ati ọpọlọpọ eniyan mìíràn wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji Dafidi ọba. Ṣimei ń wí fún Dafidi bí ó ti ń ṣépè pé, “Kúrò lọ́dọ̀ mi! Kúrò lọ́dọ̀ mi! Ìwọ apànìyàn ati eniyan lásán! Ìwọ tí o gba ìjọba mọ́ Saulu lọ́wọ́, OLUWA ń jẹ ọ́ níyà nisinsinyii, fún ọpọlọpọ eniyan tí o pa ninu ìdílé Saulu. OLUWA sì ti fi ìjọba rẹ fún Absalomu, ọmọ rẹ, ìparun ti dé bá ọ, nítorí pé apànìyàn ni ọ́.” Abiṣai, ọmọ Seruaya wí fún ọba pé, “Kí ló dé tí òkú ajá lásánlàsàn yìí fi ń ṣépè lé ọba, oluwa mi? Jẹ́ kí n lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, kí n sì sọ orí rẹ̀ kalẹ̀ kúrò ní ọrùn rẹ̀.” Ṣugbọn ọba dáhùn pé, “Kò sí ohun tí ó kan ẹ̀yin ọmọ Seruaya ninu ọ̀rọ̀ yìí. Kí ni n óo ti ṣe yín sí, ẹ̀yin ọmọ Seruaya? Bí ó bá jẹ́ pé OLUWA ni ó sọ fún un pé kí ó máa ṣépè lé mi, ta ló ní ẹ̀tọ́ láti bèèrè pé, kí ló dé tí ó fi ń ṣe bẹ́ẹ̀?” Dafidi sọ fún Abiṣai ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ṣebí ọmọ tèmi gan-an ni ó ń gbìyànjú láti pa mí yìí, kí ló dé tí ọ̀rọ̀ ti ará Bẹnjamini yìí fi wá jọ yín lójú. OLUWA ni ó ní kí ó máa ṣépè, nítorí náà, ẹ fi sílẹ̀, ẹ jẹ́ kí ó máa ṣẹ́ ẹ. Bóyá OLUWA lè wo ìpọ́njú mi, kí ó sì fi ìre dípò èpè tí ó ń ṣẹ́ lé mi.” Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ bá ń bá tiwọn lọ, Ṣimei sì ń tẹ̀lé wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ keji òkè náà, bí ó ti ń tẹ̀lé wọn, bẹ́ẹ̀ ni ó ń ṣépè, ó ń sọ òkúta lù ú, ó sì ń da erùpẹ̀ sí wọn lára. Nígbà tí ọba ati àwọn eniyan rẹ̀ yóo fi dé ibi odò Jọdani, ó ti rẹ̀ wọ́n, nítorí náà, wọ́n sinmi níbẹ̀. Absalomu ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ wọ Jerusalẹmu lọ, Ahitofeli sì wà pẹlu wọn. Nígbà tí Huṣai, ará Ariki, ọ̀rẹ́ Dafidi pàdé Absalomu, ó kígbe pé “Kí ọba kí ó pẹ́! Kí ọba kí ó pẹ́!” Absalomu bá bi í pé, “Kí ló dé, tí o kò fi ṣe olótìítọ́ sí Dafidi ọ̀rẹ́ rẹ mọ́? Kí ló dé tí o kò fi bá a lọ?” Huṣai dáhùn pé, “Ẹ̀yìn ẹnikẹ́ni tí OLUWA, ati àwọn eniyan wọnyi, ati gbogbo Israẹli bá yàn ni mo wà. Tirẹ̀ ni n óo jẹ́, n óo sì dúró tì í. Ta ni ǹ bá tilẹ̀ tún sìn, bí kò ṣe ọmọ oluwa mi. Bí mo ti sin baba rẹ, bẹ́ẹ̀ gan-an ni n óo sin ìwọ náà.” Absalomu kọjú sí Ahitofeli, ó sì bi í pé, “Nígbà tí a ti dé Jerusalẹmu báyìí, kí ni ìmọ̀ràn rẹ?” Ahitofeli dáhùn pé, “Wọlé lọ bá àwọn obinrin baba rẹ, tí ó fi sílẹ̀ láti máa tọ́jú ààfin, kí o sì bá wọn lòpọ̀. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli yóo wá gbà pé o ti kẹ̀yìn sí baba rẹ, ọkàn gbogbo àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn rẹ yóo sì balẹ̀.” Wọ́n bá pàgọ́ kan fún Absalomu, lórí òrùlé ààfin, ó wọlé lọ bá àwọn obinrin baba rẹ̀ lójú gbogbo àwọn eniyan, ó sì bá wọn lòpọ̀. Ní àkókò náà, ìmọ̀ràn tí Ahitofeli bá dá, ni àwọn eniyan máa ń gbà, bí ẹni pé Ọlọrun gan-an ni ó ń sọ̀rọ̀; Dafidi ati Absalomu pàápàá a máa tẹ̀lé ìmọ̀ràn rẹ̀. Lẹ́yìn náà, Ahitofeli wí fún Absalomu pé, “Jẹ́ kí n ṣa ẹgbaafa (12,000) ninu àwọn ọmọ ogun, kí n sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa Dafidi lọ lálẹ́ òní. N óo kọlù ú nígbà tí àárẹ̀ bá mú un; tí ọkàn rẹ̀ sì rẹ̀wẹ̀sì; ẹ̀rù yóo bà á, gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ yóo sì sá lọ. Ọba nìkan ṣoṣo ni n óo pa. N óo sì kó gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, gẹ́gẹ́ bí iyawo tí ó lọ bá ọkọ rẹ̀ nílé. Ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo ni o fẹ́ pa, àwọn eniyan yòókù yóo sì wà ní alaafia.” Ìmọ̀ràn náà dára lójú Absalomu ati gbogbo àgbààgbà Israẹli. Ṣugbọn Absalomu dáhùn pé, “Ẹ pe Huṣai wá, kí á gbọ́ ohun tí òun náà yóo sọ.” Nígbà tí Huṣai dé, Absalomu wí fún un pé, “Ìmọ̀ràn tí Ahitofeli fún wa nìyí, ṣé kí á tẹ̀lé e? Bí kò bá yẹ kí á tẹ̀lé e, sọ ohun tí ó yẹ kí á ṣe fún wa.” Huṣai dáhùn pé, “Ìmọ̀ràn tí Ahitofeli fún Kabiyesi ní àkókò yìí, kò dára. Ṣebí o mọ̀ pé, akikanju jagunjagun ni baba rẹ, ati àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀? Ara kan wọ́n báyìí, wọn yóo sì rorò ju abo ẹkùn beari tí ọdẹ jí lọ́mọ kó lọ. Bẹ́ẹ̀ sì ni jagunjagun tí ó ní ọpọlọpọ ìrírí ni baba rẹ, kò sì ní sùn lọ́dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ ní alẹ́ yìí. Bóyá bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí, ninu ihò ilẹ̀ níbìkan ni ó wà tabi ibòmíràn. Bí Dafidi bá kọlu àwọn eniyan rẹ, tí wọ́n sì pa díẹ̀ ninu wọn, àwọn tí wọ́n bá gbọ́ yóo wí pé wọ́n ti ṣẹgun àwọn eniyan Absalomu. Nígbà náà, ẹ̀rù yóo ba àwọn tí wọ́n jẹ́ akikanju jùlọ ninu àwọn eniyan rẹ, tí wọ́n sì láyà bíi kinniun; nítorí pé, gbogbo eniyan ní Israẹli ni ó mọ̀ pé akọni jagunjagun ni baba rẹ, akikanju sì ni àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀. Ìmọ̀ràn tèmi ni pé kí o kó gbogbo àwọn ọmọ ogun jọ jákèjádò ilẹ̀ Israẹli láti Dani títí dé Beeriṣeba, kí wọ́n pọ̀ bíi yanrìn etí òkun. Ìwọ gan-an ni kí o ṣáájú wọn lọ sí ogun náà. A óo kọlu Dafidi níbikíbi tí a bá ti bá a, a óo bò wọ́n bí ìgbà tí ìrì bá sẹ̀ sórí ilẹ̀; ẹnikẹ́ni kò sì ní yè ninu òun ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Bí ó bá sá wọ inú ìlú kan, àwọn ọmọ Israẹli yóo fi okùn fa ìlú náà lulẹ̀ sinu àfonífojì tí ó wà ní ìsàlẹ̀. Ẹyọ òkúta kan ṣoṣo kò ní ṣẹ́kù sórí òkè náà.” Absalomu ati gbogbo Israẹli dáhùn pé, “Ìmọ̀ràn ti Huṣai dára ju ti Ahitofeli lọ,” nítorí pé OLUWA ti pinnu láti yí ìmọ̀ràn rere tí Ahitofeli mú wá pada, kí ibi lè bá Absalomu. Huṣai bá lọ sọ fún Sadoku ati Abiatari, àwọn alufaa mejeeji, irú ìmọ̀ràn tí Ahitofeli fún Absalomu ati àwọn ọmọ Israẹli, ati èyí tí òun fún wọn. Huṣai tún fi kún un pé, kí wọ́n ranṣẹ kíákíá lọ sọ fún Dafidi pé, kò gbọdọ̀ sùn níbi tí wọ́n ti ń ré odò Jọdani kọjá ninu aṣálẹ̀ ní òru ọjọ́ náà. Ó gbọdọ̀ kọjá sí òdìkejì odò lẹsẹkẹsẹ kí ọwọ́ má baà tẹ̀ ẹ́ ati àwọn eniyan tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì pa wọ́n. Jonatani ati Ahimaasi dúró sí ibi orísun Enrogeli, ní ìgbèríko ati máa lọ sí Jerusalẹmu, nítorí pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ fojú kàn wọ́n, pé wọ́n wọ ìlú rárá. Iranṣẹbinrin kan ni ó máa ń lọ sọ ohun tí ó bá ti ṣẹlẹ̀ fún wọn, àwọn náà á lọ sọ fún Dafidi. Ṣugbọn ọmọkunrin kan rí wọn, ó sì sọ fún Absalomu. Jonatani ati Ahimaasi bá sáré lọ fi ara pamọ́ ní ilé ọkunrin kan ní Bahurimu. Ọkunrin yìí ní kànga kan ní àgbàlá ilé rẹ̀. Àwọn mejeeji bá kó sinu kànga náà. Aya ọkunrin náà fi nǹkan dé e lórí, ó sì da ọkà bàbà lé e kí ẹnikẹ́ni má baà fura sí i. Nígbà tí àwọn iranṣẹ Absalomu dé ọ̀dọ̀ obinrin náà, wọ́n bi í pé, “Níbo ni Ahimaasi ati Jonatani wà?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Wọ́n ti kọjá sí òdìkejì odò.” Àwọn ọkunrin náà wá wọn títí, ṣugbọn wọn kò rí wọn. Wọ́n bá pada lọ sí Jerusalẹmu. Nígbà tí àwọn ọkunrin náà lọ tán, Ahimaasi ati Jonatani jáde ninu kànga, wọ́n sì lọ ròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Dafidi. Wọ́n sọ ohun tí Ahitofeli ti gbèrò láti ṣe sí Dafidi. Wọ́n ní kí ó yára, kí ó rékọjá sí òdìkejì odò náà kíá. Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí rékọjá sí òdìkejì odò Jọdani. Nígbà tí ilẹ̀ yóo fi mọ́, gbogbo wọn ti kọjá tán. Nígbà tí Ahitofeli rí i pé, Absalomu kò tẹ̀lé ìmọ̀ràn tí òun fún un, ó di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó pada lọ sí ìlú rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó ti ṣètò ilé rẹ̀, ó pokùnso, ó bá kú; wọ́n sì sin ín sí ibojì ìdílé rẹ̀. Nígbà tí Absalomu ati àwọn ọmọ Israẹli yóo fi ré odò Jọdani kọjá tán, Dafidi ti dé ìlú tí wọn ń pè ní Mahanaimu. Amasa ni Absalomu fi ṣe olórí ogun rẹ̀, dípò Joabu. Itira ará Iṣimaeli ni baba Amasa. Ìyá rẹ̀ sì ni Abigaili, ọmọbinrin Nahaṣi, arabinrin Seruaya, ìyá Joabu. Absalomu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pàgọ́ sí ilẹ̀ Gileadi. Nígbà tí Dafidi dé Mahanaimu, Ṣobi, ọmọ Nahaṣi, wá pàdé rẹ̀, láti ìlú Raba, ní ilẹ̀ Amoni. Makiri, ọmọ Amieli, náà wá, láti Lodebari; ati Basilai, láti Rogelimu, ní ilẹ̀ Gileadi. Wọ́n kó ibùsùn lọ́wọ́ wá fún wọn, ati àwo, ìkòkò ati ọkà baali, ọkà tí wọ́n ti lọ̀, ati èyí tí wọ́n ti yan, erèé ati ẹ̀fọ́; oyin, omi wàrà, ati wàrà sísè. Wọ́n sì kó aguntan wá pẹlu, láti inú agbo wọn fún Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀, kí wọ́n lè rí nǹkan jẹ. Nítorí wọ́n rò pé yóo ti rẹ̀ wọ́n, ebi yóo ti máa pa wọ́n, òùngbẹ yóo sì ti máa gbẹ wọ́n, ninu aṣálẹ̀ tí wọ́n wà. Dafidi kó gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ jọ, ó pín wọn ní ọgọọgọrun-un (100) ati ẹgbẹẹgbẹrun (1,000), ó fi balogun kọ̀ọ̀kan ṣe olórí ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn náà, ó rán wọn jáde ní ìpín mẹta, ó fi Joabu, ati Abiṣai, ọmọ Seruaya, àbúrò Joabu, ati Itai, ará Gati, ṣe ọ̀gágun àgbà ìpín kọ̀ọ̀kan. Ó ní òun pàápàá yóo bá wọn lọ. Ṣugbọn wọ́n dá a lóhùn pé, “O kò ní bá wa lọ, nítorí pé bí a bá sá lójú ogun ní tiwa, tabi tí ìdajì ninu wa bá kú, kò jẹ́ ohunkohun fún àwọn ọ̀tá wa. Ṣugbọn ìwọ nìkan ju ẹgbaarun (10,000) wa lọ. Ohun tí ó dára ni pé kí o dúró ní ìlú, kí o sì máa fi nǹkan ranṣẹ sí wa láti fi ràn wá lọ́wọ́.” Ọba dáhùn pé, “Ohunkohun tí ẹ bá ní kí n ṣe náà ni n óo ṣe.” Ọba bá dúró ní ẹnu ibodè, bí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí ń tò kọjá lọ ní ọgọọgọrun-un (100) ati ẹgbẹẹgbẹrun (1,000). Ó pàṣẹ fún Joabu, ati Abiṣai, ati Itai, ó ní, “Nítorí tèmi, ẹ má pa Absalomu lára.” Gbogbo àwọn ọmọ ogun sì gbọ́ nígbà tí Dafidi ń pa àṣẹ yìí fún àwọn ọ̀gágun rẹ̀. Àwọn ọmọ ogun náà bá jáde lọ sinu pápá láti bá àwọn ọmọ ogun Israẹli jà, ní aṣálẹ̀ Efuraimu. Àwọn ọmọ ogun Dafidi ṣẹgun àwọn ọmọ ogun Israẹli. Wọ́n pa wọ́n ní ìpakúpa ní ọjọ́ náà. Àwọn tí wọ́n kú lára wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ kan (20,000). Ogun náà tàn káàkiri gbogbo agbègbè; àwọn tí wọ́n sì sọnù sinu igbó pọ̀ ju àwọn tí wọ́n fi idà pa lójú ogun lọ. Lójijì, Absalomu já sí ààrin àwọn ọmọ ogun Dafidi. Ìbaaka ni Absalomu gùn. Ìbaaka yìí gba abẹ́ ẹ̀ka igi Oaku ńlá kan, ẹ̀ka igi yìí sì dí tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi kọ́ Absalomu ní irun orí, Ìbaaka yọ lọ lábẹ́ rẹ̀, Absalomu sì ń rọ̀ dirodiro nítorí pé ẹsẹ̀ rẹ̀ kò tólẹ̀. Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun Dafidi rí i, ó bá lọ sọ fún Joabu pé òun rí Absalomu tí ó ń rọ̀ lórí igi Oaku. Joabu dá a lóhùn pé, “Nígbà tí o rí i, kí ló dé tí o kò pa á níbẹ̀ lẹsẹkẹsẹ? Inú mi ìbá dùn láti fún ọ ní owó fadaka mẹ́wàá ati ìgbànú akikanju ninu ogun jíjà.” Ṣugbọn ọmọ ogun náà dáhùn pé, “Ò báà tilẹ̀ fún mi ní ẹgbẹrun (1,000) owó fadaka, n kò ní ṣíwọ́ sókè pa ọmọ ọba. Gbogbo wa ni a gbọ́, nígbà tí ọba pàṣẹ fún ìwọ ati Abiṣai ati Itai pé, nítorí ti òun ọba, kí ẹ má pa Absalomu lára. Tí mo bá ṣe àìgbọràn sí òfin ọba, tí mo sì pa Absalomu, ó pẹ́ ni, ó yá ni, ọba yóo gbọ́, bí ọba bá sì gbọ́, ìwọ gan-an kò ní gbà mí sílẹ̀.” Joabu dáhùn pé, “N kò ní máa fi àkókò mi ṣòfò, kí n sọ pé mò ń bá ọ sọ̀rọ̀.” Joabu bá mú ọ̀kọ̀ mẹta, ó sọ wọ́n lu Absalomu ní igbá àyà lórí igi oaku tí ó há sí. Mẹ́wàá ninu àwọn ọdọmọkunrin tí wọn ń ru ihamọra Joabu bá yí Absalomu po, wọ́n sì ṣá a pa. Lẹ́yìn náà, Joabu fọn fèrè ogun, kí wọ́n dáwọ́ ogun jíjà dúró. Àwọn ọmọ ogun Dafidi bá pada lẹ́yìn àwọn ọmọ ogun Israẹli. Wọ́n gbé òkú Absalomu jù sinu ihò jíjìn kan ninu igbó, wọ́n sì kó ọpọlọpọ òkúta jọ sórí òkú rẹ̀. Gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli bá sá, olukuluku gba ilé rẹ̀ lọ. Nígbà ayé Absalomu, ó ṣe ọ̀wọ̀n ìrántí kan fún ara rẹ̀ ní àfonífojì ọba, nítorí kò ní ọmọkunrin kankan tí ó le gbé orúkọ rẹ̀ ró. Nítorí náà ni ó ṣe sọ ọ̀wọ̀n náà ní orúkọ ara rẹ̀; ọ̀wọ̀n Absalomu ni wọ́n ń pe ọ̀wọ̀n náà, títí di òní olónìí. Ahimaasi, ọmọ Sadoku bá sọ fún Joabu pé, “Jẹ́ kí n sáré tọ ọba lọ, kí n sì fún un ní ìròyìn ayọ̀ náà, pé OLUWA ti gbà á lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀.” Ṣugbọn Joabu dá a lóhùn pé, “Rárá o, kì í ṣe ìwọ ni o óo mú ìròyìn náà lọ lónìí, bí ó bá di ọjọ́ mìíràn, o lè mú ìròyìn ayọ̀ lọ. Kì í ṣe òní, nítorí pé ọmọ ọba ni ó kú.” Joabu bá sọ fún ọ̀kan ninu àwọn ará Kuṣi pé, “Lọ sọ ohun tí o rí fún ọba.” Ará Kuṣi náà bá tẹríba fún Joabu, ó sì sáré lọ. Ṣugbọn Ahimaasi ṣá tẹnu mọ́ ọn pé, “N kò kọ ohunkohun tí ó lè ṣẹlẹ̀, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n sáré tẹ̀lé ará Kuṣi náà lọ.” Joabu bi í pé, “Kí ló dé tí o fi fẹ́ lọ, ọmọ mi? Kò sí èrè kankan fún ọ níbẹ̀.” Ahimaasi dáhùn pé, “Mo ṣá fẹ́ lọ ni, ohun yòówù tí ó lè ṣẹlẹ̀.” Joabu dáhùn pé, “Ǹjẹ́ bí o bá fẹ́, máa lọ.” Ahimaasi bá sáré gba ọ̀nà pẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ, ó sì ṣáájú ará Kuṣi náà. Dafidi wà ní àlàfo tí ó wà ní ààrin ẹnu ọ̀nà tinú ati ti òde, ní ẹnu ibodè ìlú. Ẹ̀ṣọ́ tí ń ṣọ́ bodè gun orí odi lọ, ó dúró lé orí òrùlé ẹnubodè. Bí ó ṣe gbé ojú sókè, ó rí ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo tí ó ń sáré bọ̀. Ó pe ọba nísàlẹ̀, ó sì sọ fún un, ọba bá dáhùn pé, “Bí ó bá jẹ́ òun nìkan ni, ìròyìn ayọ̀ ni ó ń mú bọ̀.” Ẹni tí ń sáré bọ̀ náà túbọ̀ ń súnmọ́ tòsí. Ẹ̀ṣọ́ náà tún rí ẹyọ ẹnìkan, tí òun náà ń sáré bọ̀. Ó tún ké sí ẹ̀ṣọ́ tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà, ó ní, “Wò ó, ẹnìkan ni ó tún ń sáré bọ̀ yìí.” Ọba dáhùn pé, “Ìròyìn ayọ̀ ni òun náà ń mú bọ̀.” Ẹ̀ṣọ́ tún ní, “Ẹni tí ó ṣáájú tí mo rí yìí jọ Ahimaasi.” Ọba dáhùn pé, “Eniyan dáradára ni, ìròyìn ayọ̀ ni ó sì ń mú bọ̀.” Ahimaasi bá kígbe sókè pé, “Alaafia ni!” Ó wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀ níwájú ọba, ó sì wí fún un pé, “Ìyìn ni fún OLUWA Ọlọrun rẹ tí ó fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọba, oluwa mi.” Ọba bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé nǹkankan kò ṣe Absalomu ọmọ mi?” Ahimaasi dá ọba lóhùn pé, “Kabiyesi, nígbà tí Joabu fi ń rán mi bọ̀, gbogbo nǹkan dàrú, ó sì rí rúdurùdu, nítorí náà n kò lè sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ gan-an.” Ọba bá ní kí ó dúró ní ẹ̀gbẹ́ kan ná, ó bá dúró. Lẹ́yìn náà, ará Kuṣi náà dé, ó sì wí fún ọba pé, “Ìròyìn ayọ̀ ni mo mú wá fún oluwa mi, ọba! Nítorí pé, OLUWA ti fún ọ ní ìṣẹ́gun lónìí lórí gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ pa ọ́.” Ọba bi í pé, “Ṣé alaafia ni Absalomu, ọmọ mi wà?” Ará Kuṣi náà dáhùn pé, “Kí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Absalomu ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ, ati gbogbo àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọ.” Ìbànújẹ́ ńlá dé bá ọba, ó bá gun òkè lọ sinu yàrá tí ó wà lókè ẹnu ọ̀nà ibodè, ó sì sọkún. Bí ó ti ń lọ, bẹ́ẹ̀ ni ó ń ké pé, “Ha! Ọmọ mi! Absalomu, ọmọ mi! Absalomu, ọmọ mi! Ọmọ mi! Kì bá ṣe pé ó ṣeéṣe ni, kí n kú dípò rẹ, Absalomu, ọmọ mi, ọmọ mi!” Àwọn kan lọ sọ fún Joabu pé, ọba ń sọkún, ó sì ń ṣọ̀fọ̀ Absalomu. Nítorí náà, ìṣẹ́gun ọjọ́ náà pada di ìbànújẹ́ fún gbogbo àwọn eniyan; nítorí wọ́n gbọ́ pé ọba ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀. Àwọn ọmọ ogun náà yọ́ wọ ìlú jẹ́ẹ́, bí ẹni pé wọ́n sá lójú ogun, tí ìtìjú sì mú wọn. Ọba dọwọ́ bojú, ó ń sọkún, ó sì ń kígbe sókè pé, “Ọmọ mi! Absalomu, ọmọ mi! Absalomu, ọmọ mi!” Joabu bá wọlé tọ ọba lọ, ó wí fún un pé, “O ti dójúti àwọn ọmọ ogun rẹ lónìí, àwọn tí wọ́n gba ẹ̀mí rẹ là, ati ẹ̀mí àwọn ọmọ rẹ, ati ti àwọn aya rẹ, ati àwọn obinrin rẹ; nítorí pé o fẹ́ràn àwọn tí wọ́n kórìíra rẹ, o sì kórìíra àwọn tí wọ́n fẹ́ràn rẹ. O ti fihàn gbangba pé, àwọn ọ̀gágun ati ọmọ ogun rẹ kò jẹ́ nǹkankan lójú rẹ. Mo ti rí i gbangba lónìí pé, ìbá dùn mọ́ ọ ninu, bí gbogbo wa tilẹ̀ kú, tí Absalomu sì wà láàyè. Yára dìde, kí o lọ tu àwọn ọmọ ogun ninu; nítorí pé mo fi OLUWA búra pé, bí o kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, kò ní ku ẹnìkan ninu wọn pẹlu rẹ ní òwúrọ̀ ọ̀la. Èyí yóo wá burú ju gbogbo ibi tí ó ti bá ọ láti ìgbà èwe rẹ títí di òní lọ.” Ọba bá dìde, ó lọ jókòó lẹ́bàá ẹnu ọ̀nà ibodè. Àwọn eniyan rẹ̀ gbọ́ pé ó wà níbẹ̀, gbogbo wọn bá wá rọ̀gbà yí i ká. Ní àkókò yìí, gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli ti sá, olukuluku ti pada sí ilé rẹ̀. Ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli káàkiri. Wọ́n ń wí láàrin ara wọn pé, “Ọba Dafidi ni ó gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, òun ni ó gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Filistia, ṣugbọn nisinsinyii, ó ti sá kúrò nílùú fún Absalomu. A fi àmì òróró yan Absalomu ní ọba, ṣugbọn wọ́n ti pa á lójú ogun, nítorí náà, ó yẹ kí ẹnìkan gbìyànjú láti mú Dafidi ọba pada.” Ìròyìn ohun tí àwọn eniyan Israẹli ń wí kan Dafidi ọba lára. Dafidi ọba ranṣẹ sí àwọn alufaa mejeeji: Sadoku, ati Abiatari, láti bèèrè lọ́wọ́ àwọn àgbààgbà Juda pé, “Kí ló dé tí ẹ fi níláti gbẹ́yìn ninu ètò àtidá ọba pada sí ààfin rẹ̀? Ṣebí ìbátan ọba ni yín, ẹ̀jẹ̀ kan náà sì ni yín? Kí ló dé tí ẹ fi níláti gbẹ́yìn ninu ètò àtidá ọba pada sí ààfin rẹ̀.” Dafidi ní kí wọ́n sọ fún Amasa pé, ẹbí òun ni Amasa; ati pé, láti ìgbà náà lọ, Amasa ni òun yóo fi ṣe balogun òun, dípò Joabu. Ó búra pé kí Ọlọrun pa òun bí òun kò bá ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀rọ̀ tí Dafidi sọ yìí, mú kí àwọn eniyan Juda fara mọ́ ọn, wọ́n sì ranṣẹ sí i pé kí ó pada pẹlu gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀. Nígbà tí ọba ń pada bọ̀, àwọn eniyan Juda wá sí Giligali láti pàdé rẹ̀ ati láti mú un kọjá odò Jọdani. Ní àkókò yìí kan náà, Ṣimei, ọmọ Gera, ará Bẹnjamini, láti ìlú Bahurimu, sáré lọ sí odò Jọdani láti pàdé Dafidi ọba pẹlu àwọn eniyan Juda. Ẹgbẹrun (1,000) eniyan, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, ni ó kó lọ́wọ́. Siba, iranṣẹ ìdílé Saulu, náà wá pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀ mẹẹdogun, ati ogún iranṣẹ. Wọ́n dé sí etí odò kí ọba tó dé ibẹ̀. Wọ́n rékọjá odò sí òdìkejì, láti dara pọ̀ mọ́ àwọn tí wọn yóo sin ìdílé ọba kọjá odò, ati láti ṣe ohunkohun tí ọba bá fẹ́. Bí ọba ti múra láti kọjá odò náà, Ṣimei wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó ní, “Kabiyesi, jọ̀wọ́ má dá mi lẹ́bi, má sì ranti àṣìṣe tí mo ṣe ní ọjọ́ tí o kúrò ní Jerusalẹmu, jọ̀wọ́ gbàgbé rẹ̀. Mo mọ̀ pé mo ti ṣẹ̀; Ìdí nìyí, tí ó fi jẹ́ pé èmi ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó kọ́ wá pàdé rẹ lónìí, ninu gbogbo ìdílé Josẹfu.” Abiṣai ọmọ Seruaya dáhùn pé, “Pípa ni ó yẹ kí á pa Ṣimei nítorí pé ó ṣépè lé ẹni tí OLUWA fi òróró yàn ní ọba.” Ṣugbọn Dafidi dá Abiṣai ati Joabu ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lóhùn pé, “Kí ló kàn yín ninu ọ̀rọ̀ yìí? Kí ni n óo ti ṣe yín sí, ẹ̀yin ọmọ Seruaya, tí ẹ̀ ń ṣe bí ọ̀tá sí mi? Èmi ni ọba Israẹli lónìí, ẹnìkan kò sì ní pa ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli.” Ó bá dá Ṣimei lóhùn, ó ní, “Mo búra fún ọ pé ẹnikẹ́ni kò ní pa ọ́.” Lẹ́yìn náà, Mẹfiboṣẹti, ọmọ ọmọ Saulu, wá pàdé ọba. Láti ìgbà tí ọba ti kúrò ní Jerusalẹmu, títí tí ó fi pada dé ní alaafia, Mẹfiboṣẹti kò fọ ẹsẹ̀ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni kò gé irùngbọ̀n rẹ̀, tabi kí ó fọ aṣọ rẹ̀. Nígbà tí Mẹfiboṣẹti ti Jerusalẹmu dé láti pàdé ọba, ọba bi í pé, “Mẹfiboṣẹti, kí ló dé tí o kò fi bá mi lọ?” Mẹfiboṣẹti dáhùn pé, “Kabiyesi, gẹ́gẹ́ bí ìwọ náà ti mọ̀, arọ ni mí. Mo sọ fún iranṣẹ mi pé kí ó di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mi ní gàárì, kí n lè gùn ún tẹ̀lé ọ, ṣugbọn ó hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí mi. Ó lọ pa irọ́ mọ́ mi lọ́dọ̀ ọba. Ṣugbọn bí angẹli Ọlọrun ni oluwa mi, ọba rí; nítorí náà, ṣe ohun tí ó bá tọ́ sí mi ní ojú rẹ. Gbogbo ìdílé baba mi pátá ni ó yẹ kí o pa, ṣugbọn o gbà mí láàyè; o sì fún mi ní ẹ̀tọ́ láti máa jẹun níbi tabili rẹ. Kò yẹ mí rárá, láti tún bèèrè nǹkankan mọ́ lọ́wọ́ kabiyesi.” Ọba dá a lóhùn pé, “Má wulẹ̀ tún sọ nǹkankan mọ́, mo ti pinnu pé ìwọ ati Siba ni yóo pín gbogbo ogun Saulu.” Mẹfiboṣẹti bá dáhùn pé, “Jẹ́ kí Siba máa mú gbogbo rẹ̀, kìkì pé kabiyesi pada dé ilé ní alaafia ti tó fún mi.” Basilai ará Gileadi náà wá láti Rogelimu. Ó bá ọba dé odò Jọdani láti sìn ín kọjá odò náà. Basilai ti darúgbó gan-an, ẹni ọgọrin ọdún ni. Ó tọ́jú nǹkan jíjẹ fún ọba nígbà tí ó fi wà ní Mahanaimu, nítorí pé ọlọ́rọ̀ ni. Ọba wí fún un pé, “Bá mi kálọ sí Jerusalẹmu, n óo sì tọ́jú rẹ dáradára.” Ṣugbọn Basilai dáhùn pé, “Ọjọ́ tí ó kù fún mi láyé kò pọ̀ mọ́, kí ni n óo tún máa bá kabiyesi lọ sí Jerusalẹmu fún? Mo ti di ẹni ọgọrin ọdún, kò sì sí ohunkohun tí ó tún wù mí mọ́. Oúnjẹ ati ohun mímu kò dùn lẹ́nu mi mọ́. Bí àwọn akọrin ń kọrin, n kò lè gbọ́ orin wọn mọ́. Wahala lásán ni n óo lọ kó bá oluwa mi, ọba. Irú anfaani ńlá báyìí kò tọ́ sí mi láti ọ̀dọ̀ ọba, nítorí náà, n óo bá ọba gun òkè odò Jọdani, n óo sì bá ọ lọ sí iwájú díẹ̀ ni. Lẹ́yìn náà, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n pada lọ sí ilé mi, kí n lè kú sí ìlú mi, nítòsí ibojì àwọn òbí mi. Kimhamu ọmọ mi nìyí, jẹ́ kí ó máa bá ọ lọ, kí o sì ṣe ohun tí ó bá tọ́ ní ojú rẹ fún un.” Ọba dáhùn pé, “N óo máa mú Kimhamu lọ, ohunkohun tí ó bá sì bèèrè, ni n óo ṣe fún un.” Lẹ́yìn náà ni Dafidi ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ gòkè odò Jọdani. Ó kí Basilai, ó fi ẹnu kò ó ní ẹnu, ó sì súre fún un; Basilai bá pada sí ilé rẹ̀. Lẹ́yìn tí àwọn ará ilẹ̀ Juda, ati ìdajì àwọn ọmọ Israẹli ti sin ọba kọjá odò, ọba lọ sí Giligali, Kimhamu sì bá a lọ. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá wá sọ́dọ̀ ọba, wọ́n sì bi í pé, “Kabiyesi, kí ló dé tí àwọn eniyan Juda, àwọn arakunrin wa, fi lérò pé àwọn ní ẹ̀tọ́ láti mú ọ lọ, ati láti sin ìwọ ati ìdílé rẹ, ati àwọn eniyan rẹ kọjá odò Jọdani?” Àwọn eniyan Juda bá dáhùn pé, “Ìdí tí a fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé, ọ̀kan náà ni àwa ati ọba. Kí ló dé tí èyí fi níláti bà yín ninu jẹ́? Kì í ṣá ṣe pé òun ni ó ń bọ́ wa, a kò sì gba nǹkankan lọ́wọ́ rẹ̀.” Àwọn ọmọ Israẹli dáhùn pé, “Ìlọ́po mẹ́wàá ẹ̀tọ́ tí ẹ ní sí ọba ni àwa ní, kì báà tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀kan náà ni yín. Kí ló dé tí ẹ fi fi ojú tẹmbẹlu wa? Ẹ má gbàgbé pé àwa ni a dábàá ati mú ọba pada sílé.” Ṣugbọn ọ̀rọ̀ àwọn ará ilẹ̀ Juda le ju ti àwọn ará ilẹ̀ Israẹli lọ. Aláìníláárí ẹ̀dá kan wà ní ààrin àwọn ará Giligali tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣeba, ọmọ Bikiri, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini. Ọkunrin yìí fọn fèrè, ó ní, “Kò sí ohun tí ó kàn wá pẹlu Dafidi, a kò sì ní ìpín nílé ọmọ Jese. Ẹ pada sí ilé yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.” Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá pada lẹ́yìn Dafidi, wọ́n tẹ̀lé Ṣeba. Ṣugbọn àwọn eniyan Juda tẹ̀lé Dafidi, ọba wọn, pẹlu ẹ̀mí òtítọ́, láti odò Jọdani títí dé Jerusalẹmu. Nígbà tí Dafidi pada dé ààfin rẹ̀ ní Jerusalẹmu, ó mú àwọn obinrin rẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó fi sílẹ̀, pé kí wọ́n máa tọ́jú ààfin, ó fi wọ́n sinu ilé kan pẹlu olùṣọ́, ó sì ń pèsè oúnjẹ fún wọn, ṣugbọn kò bá wọn lòpọ̀ mọ́. Ninu ìhámọ́ ni wọ́n wà, tí wọ́n ń gbé bí opó, títí tí wọ́n fi kú. Lẹ́yìn náà, ọba sọ fún Amasa pé, “Pe gbogbo àwọn ọkunrin Juda jọ, kí o sì kó wọn wá sọ́dọ̀ mi láàrin ọjọ́ mẹta; kí ìwọ náà sì wá.” Amasa bá lọ kó àwọn eniyan Juda jọ, ṣugbọn kò dé títí àkókò tí ọba dá fún un fi kọjá. Ọba bá pe Abiṣai, ó ní, “Ìyọnu tí Ṣeba yóo kó bá wa yóo ju ti Absalomu lọ. Nítorí náà, kó àwọn eniyan mi lẹ́yìn kí o sì máa lépa rẹ̀ lọ. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó lè gba àwọn ìlú olódi bíi mélòó kan kí ó sì dá wahala sílẹ̀ fún wa.” Gbogbo àwọn ọmọ ogun Joabu, ati àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun yòókù, tí wọ́n kù ní Jerusalẹmu bá tẹ̀lé Abiṣai láti lépa Ṣeba. Nígbà tí wọ́n dé ibi òkúta ńlá kan, tí ó wà ní Gibeoni, Amasa lọ pàdé wọn. Ẹ̀wù ọmọ ogun ni Joabu wọ̀; ó sán ìgbànú kan, idà rẹ̀ sì wà ninu àkọ̀ lára ìgbànú tí ó ti sán mọ́ ìbàdí. Bí Joabu ti rìn siwaju bẹ́ẹ̀ ni idà yìí bọ́ sílẹ̀. Ó bá bèèrè lọ́wọ́ Amasa pé, “Ṣé alaafia ni, arakunrin mi?” Ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbá Amasa ní irùngbọ̀n mú, bí ẹni pé ó fẹ́ fi ẹnu kò ó ní ẹnu. Amasa kò fura rárá pé idà wà ní ọwọ́ Joabu. Joabu bá gún un ní idà níkùn, gbogbo ìfun rẹ̀ tú jáde. Amasa kú lẹsẹkẹsẹ, láì jẹ́ pé Joabu tún gún un ní idà lẹẹkeji. Joabu ati Abiṣai arakunrin rẹ̀ bá ń lépa Ṣeba lọ. Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun Joabu dúró ti òkú Amasa, ó sì ń kígbe pé, “Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe ti Joabu ati ti Dafidi tẹ̀lé Joabu.” Òkú Amasa, tí ẹ̀jẹ̀ ti bò, wà ní ojú ọ̀nà gbangba, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń kọjá, tí ó bá rí i ń dúró. Nígbà tí ọkunrin tí ó dúró ti òkú náà rí i pé gbogbo eniyan ní ń dúró, ó wọ́ òkú náà kúrò lójú ọ̀nà, sinu igbó, ó sì fi aṣọ bò ó. Nígbà tí ó wọ́ ọ kúrò lójú ọ̀nà tán, gbogbo àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí sá tẹ̀lé Joabu, wọ́n ń lépa Ṣeba lọ. Ṣeba la ilẹ̀ gbogbo ẹ̀yà Israẹli já, ó lọ sí ìlú Abeli ti Beti Maaka. Gbogbo àwọn ará Bikiri bá péjọ, wọ́n sì tẹ̀lé e wọnú ìlú náà. Àwọn ọmọ ogun Joabu bá lọ dó ti ìlú náà, wọ́n fi erùpẹ̀ mọ òkítì gíga sára odi rẹ̀ lóde, wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí gbẹ́ odi náà lábẹ́, wọ́n fẹ́ wó o lulẹ̀. Obinrin ọlọ́gbọ́n kan wà ninu ìlú náà, tí ó kígbe láti orí odi, ó ní, “Ẹ tẹ́tí, ẹ gbọ́! Ẹ sọ fún Joabu kí ó wá gbọ́! Mo ní ọ̀rọ̀ kan tí mo fẹ́ bá a sọ.” Joabu bá lọ sibẹ. Obinrin náà bèèrè pé, “Ṣé ìwọ ni Joabu?” Joabu dáhùn pé, “Èmi ni.” Obinrin náà ní, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ tí èmi, iranṣẹbinrin rẹ fẹ́ sọ.” Joabu dá a lóhùn pé, “Mò ń gbọ́.” Obinrin yìí ní, “Nígbà àtijọ́, wọn a máa wí pé, ‘Bí ọ̀rọ̀ kan bá ta kókó, ìlú Abeli ni wọ́n ti í rí ìtumọ̀ rẹ̀.’ Lóòótọ́ sì ni, ibẹ̀ gan-an ni wọ́n tií rí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀. Abeli jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ìlú tí ó fẹ́ alaafia, tí ó sì jẹ́ olóòótọ́ jùlọ ní Israẹli. Ṣé o wá fẹ́ pa ìlú tí ó jẹ́ ìyá ní Israẹli run ni? Kí ló dé tí o fi fẹ́ pa nǹkan OLUWA run?” Joabu dáhùn pé, “Rárá o! Kò sí ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀. Kì í ṣe ìlú yìí ni mo fẹ́ parun. Ọkunrin kan, tí ń jẹ́ Ṣeba, ọmọ Bikiri, láti agbègbè olókè ti Efuraimu, ni ó ń dìtẹ̀ mọ́ Dafidi ọba. Bí o bá ti fa òun nìkan ṣoṣo kalẹ̀, n óo kúrò ní ìlú yín.” Obinrin yìí bá dáhùn pé, “A óo ju orí rẹ̀ sílẹ̀ sí ọ, láti orí odi.” Obinrin yìí bá tọ gbogbo àwọn ará ìlú lọ, ó sì fi ọgbọ́n bá wọn sọ̀rọ̀. Wọ́n bá gé orí Ṣeba, wọ́n jù ú sí Joabu láti orí odi. Joabu bá fọn fèrè ogun, gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì fi ìlú náà sílẹ̀, wọ́n pada sí ilé. Joabu bá pada lọ sọ́dọ̀ ọba, ní Jerusalẹmu. Joabu ni balogun àwọn ọmọ ogun ní Israẹli. Bẹnaya ọmọ Jehoiada sì ní olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba. Adoramu ni olórí àwọn tí wọ́n ń kó àwọn eniyan ṣiṣẹ́. Jehoṣafati ọmọ Ahiludi ni olùtọ́jú àwọn àkọsílẹ̀ ní ààfin ọba. Ṣefa ni akọ̀wé gbọ̀ngàn ìdájọ́ rẹ̀. Sadoku ati Abiatari ni alufaa. Ira, ará ìlú Jairi náà jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn alufaa Dafidi. Ní àkókò ìjọba Dafidi, ìyàn ńlá kan mú, fún odidi ọdún mẹta. Dafidi bá lọ wádìí ọ̀rọ̀ náà lọ́dọ̀ OLUWA. OLUWA sì dáhùn pé, “Saulu ati ìdílé rẹ̀ jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn, nítorí pé ó pa àwọn ará Gibeoni.” Àwọn ará Gibeoni kì í ṣe ara àwọn ọmọ Israẹli. Ara àwọn ará Amori tí wọ́n ṣẹ́kù ni wọ́n. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Israẹli ti ṣèlérí pé àwọn kò ní pa wọ́n, sibẹsibẹ Saulu gbìyànjú láti pa wọ́n run, nítorí ìtara rẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli ati Juda. Dafidi bá pe àwọn ará Gibeoni, ó sì bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ fẹ́ kí n ṣe fun yín? Ọ̀nà wo ni mo lè gbà ṣe àtúnṣe ibi tí wọ́n ṣe si yín, kí ẹ baà lè súre fún àwọn eniyan OLUWA?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Aáwọ̀ tí ó wà láàrin àwa ati Saulu ati ìdílé rẹ̀, kì í ṣe ohun tí a lè fi wúrà ati fadaka parí, a kò sì fẹ́ pa ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli.” Dafidi bá tún bèèrè pé, “Kí ni ẹ wá fẹ́ kí n ṣe fun yín?” Wọ́n dáhùn pé, “Saulu fẹ́ pa wá run, kò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ninu wa wà láàyè níbikíbi, ní ilẹ̀ Israẹli. Nítorí náà, fún wa ní meje ninu àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, kí á lè so wọ́n kọ́ níwájú OLUWA ní Gibea, ní orí òkè OLUWA.” Dafidi dáhùn pé, “N óo kó wọn lé yín lọ́wọ́.” Ṣugbọn nítorí majẹmu tí ó wà láàrin Dafidi ati Jonatani, Dafidi kò fi ọwọ́ kan Mẹfiboṣẹti, ọmọ Jonatani, ọmọ Saulu. Ṣugbọn ó mú Arimoni ati Mẹfiboṣẹti àwọn ọmọkunrin mejeeji tí Risipa, ọmọ Aya, bí fún Saulu; ó sì tún mú àwọn ọmọ marun-un tí Merabu, ọmọbinrin Saulu, bí fún Adirieli ọmọ Basilai ará Mehola. Dafidi kó wọn lé àwọn ará Gibeoni lọ́wọ́, àwọn ará Gibeoni sì so wọ́n kọ́ sórí igi, lórí òkè níwájú OLUWA, àwọn mejeeje sì kú papọ̀. Àkókò tí wọ́n kú yìí jẹ́ àkókò ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà baali nígbà tí àkókò ìrúwé fẹ́rẹ̀ kásẹ̀ nílẹ̀. Risipa, ọmọbinrin Aya, fi aṣọ ọ̀fọ̀ pa àtíbàbà fún ara rẹ̀ lórí òkúta, níbi tí òkú àwọn tí wọ́n pa wà. Ó wà níbẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè, títí di àkókò tí òjò bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀. Ní ojúmọmọ, kò jẹ́ kí àwọn ẹyẹ jẹ wọ́n ní ọ̀sán, kò sì jẹ́ kí àwọn ẹranko burúkú fọwọ́ kàn wọ́n lóru. Nígbà tí Dafidi gbọ́ ohun tí Risipa, ọmọ Aya, obinrin Saulu ṣe, ó lọ kó egungun Saulu, ati ti Jonatani, ọmọ rẹ̀, tí ó wà lọ́dọ̀ àwọn ará Jabeṣi-Gileadi. (Àwọn ará Jabeṣi ti jí àwọn egungun náà kó kúrò ní ìta gbangba, ní ààrin ìlú ní Beti Ṣani, níbi tí àwọn ará Filistia so wọ́n kọ́ sí, ní ọjọ́ tí wọ́n pa wọ́n ní òkè Giliboa.) Láti ibẹ̀ ni ó ti kó egungun Saulu, ati ti Jonatani, ọmọ rẹ̀. Wọ́n sì kó egungun àwọn mejeeje tí wọ́n so kọ́ pẹlu. Wọ́n sin egungun Saulu, ati ti Jonatani, sinu ibojì Kiṣi, baba rẹ̀, ní Sela ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Bẹnjamini. Gbogbo ohun tí ọba pa láṣẹ ni wọ́n ṣe. Lẹ́yìn náà, ni Ọlọrun gbọ́ adura tí wọ́n ń gbà fún ilẹ̀ náà. Ogun mìíràn tún bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ará Filistia ati àwọn ọmọ Israẹli. Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ sì lọ bá àwọn ará Filistia jagun. Bí wọ́n ti ń jà, àárẹ̀ mú Dafidi. Òmìrán kan tí ń jẹ́ Iṣibibenobu, gbèrò láti pa Dafidi. Ọ̀kọ̀ Iṣibibenobu yìí wọ̀n tó ọọdunrun ṣekeli idẹ, ó sì so idà tuntun mọ́ ẹ̀gbẹ́. Ṣugbọn Abiṣai, ọmọ Seruaya, sáré wá láti ran Dafidi lọ́wọ́, ó kọlu òmìrán náà, ó sì pa á. Láti ìgbà náà ni àwọn ọmọ ogun Dafidi ti búra fún un pé, “A kò ní jẹ́ kí o bá wa lọ sí ojú ogun mọ́ kí á má baà pàdánù rẹ, nítorí pé ìwọ ni ìrètí Israẹli.” Lẹ́yìn èyí, ogun mìíràn tún bẹ́ sílẹ̀ pẹlu àwọn ará Filistia, ní Gobu, ninu ogun yìí ni Sibekai ará Huṣa ti pa Safu, ọ̀kan ninu àwọn ìran òmìrán. Ogun mìíràn tún bẹ́ sílẹ̀ pẹlu àwọn ará Filistia kan náà, ní Gobu. Ninu ogun yìí ni Elihanani ọmọ Jaareoregimu, ará Bẹtilẹhẹmu, ti pa Goliati, ará Giti, ẹni tí ọ̀pá ọ̀kọ̀ rẹ̀ nípọn tó igi òfì tí àwọn obinrin fi máa ń hun aṣọ. Ogun mìíràn tún bẹ́ sílẹ̀ ní Gati. Òmìrán kan wà níbẹ̀ tí ó fẹ́ràn ogun jíjà pupọ, ìka mẹfa mẹfa ni ó ní ní ọwọ́ kọ̀ọ̀kan, ati ẹsẹ̀ kọ̀ọ̀kan; ìka ọwọ́ ati ti ẹsẹ̀ rẹ̀ jẹ́ mẹrinlelogun. Jonatani, ọmọ Ṣimei, arakunrin Dafidi pa á, nígbà tí ó ń fi àwọn ọmọ Israẹli ṣe yẹ̀yẹ́. Láti ìran àwọn òmìrán ìlú Gati ni àwọn mẹrẹẹrin ti wá, Dafidi ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ni ó sì pa wọ́n. Nígbà tí OLUWA gba Dafidi lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ati lọ́wọ́ Saulu, Dafidi kọ orin yìí sí OLUWA pé: “OLUWA ni àpáta mi, ààbò mi, ati olùgbàlà mi; Ọlọrun mi, àpáta mi, ọ̀dọ̀ ẹni tí mo sá pamọ́ sí. Àpáta mi ati ìgbàlà mi, ààbò mi ati ibi ìpamọ́ mi, olùgbàlà mi, ìwọ ni o gbà mí lọ́wọ́ ìwà ipá. Mo ké pe OLUWA, ẹni tí ìyìn yẹ, Ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi. “Ikú yí mi káàkiri, bí ìgbì omi; ìparun sì bò mí mọ́lẹ̀ bíi ríru omi; isà òkú ya ẹnu sílẹ̀ dè mí, ewu ikú sì dojú kọ mí. Ninu ìpọ́njú mi, mo ké pe OLUWA mo ké pe Ọlọrun mi, ó gbọ́ ohùn mi láti inú tẹmpili rẹ̀; ó sì tẹ́tí sí igbe mi. “Ayé mì, ó sì wárìrì; ìpìlẹ̀ àwọn ọ̀run sì wárìrì, ó mì tìtì, nítorí ibinu Ọlọrun. Èéfín jáde láti ihò imú rẹ̀, iná ajónirun sì jáde láti ẹnu rẹ̀; ẹ̀yinná tí ó pọ́n rẹ̀rẹ̀ ń ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ jáde. Ó tẹ àwọn ọ̀run ba, ó sì sọ̀kalẹ̀; ìkùukùu tí ó ṣókùnkùn sì wà ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó gun orí Kerubu, ó fò, afẹ́fẹ́ ni ó fi ṣe ìyẹ́ tí ó fi ń fò. Ó fi òkùnkùn bo ara, ìkùukùu tí ó ṣókùnkùn, tí ó sì kún fún omi ni ó fi ṣe ìbòrí. Ẹ̀yinná tí ń jó ń jáde, láti inú ìmọ́lẹ̀ tí ó wà níwájú rẹ̀. “OLUWA sán ààrá láti ọ̀run wá, ayé sì gbọ́ ohùn ọ̀gá ògo. Ó ta ọpọlọpọ ọfà, ó sì tú wọn ká. Ó tan mànàmáná, wọ́n sì ń sá. Ìsàlẹ̀ òkun di gbangba, ìpìlẹ̀ ayé sì ṣí sílẹ̀, nígbà tí OLUWA bá wọn wí, tí ó sì fi ibinu jágbe mọ́ wọn. “OLUWA nawọ́ sílẹ̀ láti òkè wá, ó dì mí mú, ó fà mí jáde kúrò ninu omi jíjìn. Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi, tí ó lágbára; ati lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí wọ́n kórìíra mi; nítorí pé wọ́n lágbára jù mí lọ. Nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú; wọ́n gbógun tì mí, ṣugbọn OLUWA dáàbò bò mí. Ó ràn mí lọ́wọ́, ó kó mi yọ ninu ewu, ó sì gbà mí là, nítorí pé inú rẹ̀ dùn sí mi. “OLUWA fún mi ní èrè òdodo mi, ó san ẹ̀san fún mi, nítorí pé mo jẹ́ aláìlẹ́bi. Nítorí pé mo pa àwọn òfin OLUWA mọ́, n kò sì ṣe agídí, kí n yipada kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun mi. Mo ti tẹ̀lé gbogbo òfin rẹ̀, n kò sì ṣe àìgbọràn sí àwọn ìlànà rẹ̀. N kò lẹ́bi níwájú rẹ̀, mo sì ti yẹra fún ẹ̀ṣẹ̀ dídá. Nítorí náà ni OLUWA ṣe san án fún mi, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi, ati gẹ́gẹ́ bí mo ti jẹ́ mímọ́ níwájú rẹ̀. “OLUWA, ò máa ṣe olóòótọ́ sí gbogbo àwọn tí wọ́n bá hu ìwà òtítọ́ sí ọ; ò sì máa fi ara rẹ hàn bí aláìlẹ́bi, fún gbogbo àwọn tí kò ní ẹ̀bi. Ọlọrun, mímọ́ ni ọ́, sí gbogbo àwọn tí wọ́n bá mọ́, ṣugbọn o kórìíra gbogbo àwọn eniyan burúkú. Ò máa gba àwọn onírẹ̀lẹ̀, o dójú lé àwọn agbéraga, láti rẹ̀ wọ́n sílẹ̀. “OLUWA, ìwọ ni ìmọ́lẹ̀ mi, ìwọ ni o sọ òkùnkùn mi di ìmọ́lẹ̀. Nípa agbára rẹ, mo lè ṣẹgun àwọn ọ̀tá mi, mo sì lè fo odi kọjá. Ní ti Ọlọrun yìí, pípé ni ọ̀nà rẹ̀, òtítọ́ ni ìlérí OLUWA, ó sì jẹ́ apata fun gbogbo àwọn tí wọ́n bá sápamọ́ sábẹ́ ààbò rẹ̀. Ta ni Ọlọrun bí kò ṣe OLUWA? Ta sì ni àpáta ààbò bí kò ṣe Ọlọrun wa? Ọlọrun yìí ni ààbò mi tí ó lágbára, ó mú gbogbo ewu kúrò ní ọ̀nà mi. Ó fún ẹsẹ̀ mi lókun láti sáré bí àgbọ̀nrín, ó sì mú kí n wà ní àìléwu lórí àwọn òkè. Ó kọ́ mi ní ogun jíjà, tóbẹ́ẹ̀ tí mo lè lo ọrun idẹ. “O fún mi ní àpáta ìgbàlà rẹ, ìrànlọ́wọ́ rẹ ni ó sọ mí di ẹni ńlá. Ìwọ ni o kò jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tá tẹ̀ mí, bẹ́ẹ̀ ni o kò jẹ́ kí ẹsẹ̀ mí kí ó yẹ̀. Mo lépa àwọn ọ̀tá mi, mo sì ṣẹgun wọn n kò pada lẹ́yìn wọn títí tí mo fi pa wọ́n run. Mo pa wọ́n run, mo bì wọ́n lulẹ̀; wọn kò sì lè dìde mọ́; wọ́n ṣubú lábẹ́ ẹsẹ̀ mi. Ìwọ ni o fún mi lágbára láti jagun, o jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi rì lábẹ́ mi. O mú kí àwọn ọ̀tá mi sá fún mi, mo sì pa àwọn tí wọ́n kórìíra mi run. Wọ́n wá ìrànlọ́wọ́ káàkiri, ṣugbọn kò sí ẹni tí ó lè gbà wọ́n; wọ́n pe OLUWA, ṣugbọn kò dá wọn lóhùn. Mo fọ́ wọn túútúú, wọ́n sì dàbí erùpẹ̀ ilẹ̀; mo tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀, wọ́n sì dàbí ẹrọ̀fọ̀ lójú títì. “Ìwọ ni o gbà mí lọ́wọ́ ìjà àwọn eniyan mi, o sì mú kí ìjọba mi dúró lórí àwọn orílẹ̀ èdè; àwọn eniyan tí n kò mọ̀ rí di ẹni tí ó ń sìn mí. Àwọn àjèjì ń wólẹ̀ níwájú mi, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí wọ́n bá ti gbúròó mi, ni wọ́n ń mú àṣẹ mi ṣẹ. Ẹ̀rù ba àwọn àjèjì, wọ́n gbọ̀n jìnnìjìnnì jáde ní ibi ààbò wọn. “OLUWA wà láàyè, ìyìn ni fún àpáta ààbò mi. Ẹ gbé Ọlọrun mi ga, ẹni tíí ṣe àpáta ìgbàlà mi. Ọlọrun ti jẹ́ kí n gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi, ó ti tẹ orí àwọn orílẹ̀-èdè ba lábẹ́ mi; ó sì fà mí yọ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi. “OLUWA, ìwọ ni o gbé mi ga ju àwọn ọ̀tá mi lọ, o sì dáàbò bò mí, lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá. Nítorí náà, n óo máa yìn ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, n óo máa kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ. Ọlọrun fi ìṣẹ́gun ńlá fún ọba rẹ̀, ó sì fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ han ẹni tí ó fi àmì òróró yàn, àní Dafidi ati arọmọdọmọ rẹ̀ laelae!” Ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dafidi nìyí; àní, ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Dafidi, ọmọ Jese, tí a gbé ga ní Israẹli, ẹni àmì òróró Ọlọrun Jakọbu, olórin dídùn ní Israẹli: “Ẹ̀mí OLUWA ń gba ẹnu mi sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ rẹ̀ wà ní ẹnu mi. Ọlọrun Israẹli ti sọ̀rọ̀, Àpáta Israẹli ti wí fún mi pé, ‘Ẹni yòówù tí ó bá fi òtítọ́ jọba, tí ó ṣe àkóso pẹlu ìbẹ̀rù Ọlọrun, a máa tàn sí wọn bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀, bí oòrùn tí ó ń ràn ní òwúrọ̀ kutukutu, ní ọjọ́ tí kò sí ìkùukùu; ó dàbí òjò tí ń mú kí koríko hù jáde láti inú ilẹ̀.’ “Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún arọmọdọmọ mi níwájú Ọlọrun, nítorí pé, ó ti bá mi dá majẹmu ayérayé nípa ohun gbogbo, majẹmu tí kò lè yipada, ati ìlérí tí kò ní yẹ̀. Yóo ṣe ohun tí mo fẹ́ fún mi. Yóo ràn mí lọ́wọ́, yóo fún mi ní ìfẹ́ ọkàn mi. Ṣugbọn àwọn tí wọn kò mọ Ọlọrun dàbí igi ẹ̀gún tí a gbé sọnù, kò sí ẹni tí ó lè fi ọwọ́ lásán gbá wọn mú. Ẹni tí yóo fọwọ́ kan ẹ̀gún gbọdọ̀ lo ohun èlò tí a fi irin ṣe tabi igi ọ̀kọ̀, láti fi wọ́n jóná patapata.” Orúkọ àwọn ọmọ ogun Dafidi tí wọ́n jẹ́ akọni ati akikanju nìwọ̀nyí: Ekinni ni, Joṣebu-Baṣebeti, ará Takimoni, òun ni olórí ninu “Àwọn Akọni Mẹta,” ó fi ọ̀kọ̀ bá ẹgbẹrin (800) eniyan jà, ó sì pa gbogbo wọn ninu ogun kan ṣoṣo. Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni, Eleasari, ọmọ Dodo, ti ìdílé Ahohi, ó wà pẹlu Dafidi nígbà tí wọ́n pe àwọn ará Filistia níjà, tí wọ́n kó ara wọn jọ fún ogun, tí àwọn ọmọ ogun Israẹli sì sá sẹ́yìn. Ṣugbọn Eleasari dúró gbọningbọnin, ó sì bá àwọn ará Filistia jà títí tí ọwọ́ rẹ̀ fi wo koko mọ́ idà rẹ̀, tí kò sì le jù ú sílẹ̀ mọ́. OLUWA ja àjàṣẹ́gun ńlá ní ọjọ́ náà. Lẹ́yìn tí ogun náà parí ni àwọn ọmọ ogun Israẹli tó pada sí ibi tí Eleasari wà, tí wọ́n lọ kó àwọn ohun ìjà tí ó wà lára àwọn tí ogun pa. Ẹnìkẹta ninu àwọn akọni náà ni Ṣama, ọmọ Agee, ará Harari. Ní àkókò kan, àwọn ará Filistia kó ara wọn jọ sí Lehi, níbi tí oko ewébẹ̀ kan wà. Àwọn ọmọ ogun Israẹli sá fún àwọn ará Filistia, ṣugbọn Ṣama dúró gbọningbọnin ní ojú ogun. Ó jà kíkankíkan, ó sì pa àwọn ará Filistia. OLUWA sì ja àjàṣẹ́gun ńlá ní ọjọ́ náà. Nígbà tí àkókò ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè súnmọ́ tòsí, mẹta ninu àwọn ọgbọ̀n akọni náà lọ sí inú ihò àpáta tí ó wà ní Adulamu, níbi tí Dafidi wà nígbà náà, nígbà tí ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun Filistini pàgọ́ wọn sí àfonífojì Refaimu. Dafidi wà ní orí òkè kan tí wọ́n mọ odi yípo, ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun Filistini kan ti gba Bẹtilẹhẹmu, wọ́n sì wà níbẹ̀. Ọkàn ilé fa Dafidi pupọ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi wí pé, “Báwo ni ìbá ti dùn tó, kí ẹnìkan bu omi wá fún mi mu, láti inú kànga tí ó wà ní ẹnubodè Bẹtilẹhẹmu.” Àwọn akọni ọmọ ogun mẹta yìí bá fi tipátipá la àgọ́ àwọn ará Filistia kọjá, wọ́n pọn omi láti inú kànga náà, wọ́n sì gbé e wá fún Dafidi. Ṣugbọn Dafidi kọ̀, kò mu ún. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó dà á sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun mímú fún OLUWA. Ó sì wí pé, “OLUWA, kò yẹ kí n mu omi yìí, nítorí pé, yóo dàbí ẹni pé ẹ̀jẹ̀ àwọn ọkunrin mẹta yìí, tí wọ́n fi orí la ikú lọ ni mò ń mu.” Nítorí náà, ó kọ̀, kò mu ún. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí jẹ́ ara àwọn nǹkan ìgboyà tí àwọn akọni ọmọ ogun mẹta náà ṣe. Arakunrin Joabu, tí ń jẹ́ Abiṣai, ọmọ Seruaya ni aṣiwaju fún “Àwọn Ọgbọ̀n Akọni Olókìkí.” Ó fi idà rẹ̀ pa ọọdunrun eniyan, nípa bẹ́ẹ̀, ó di olókìkí láàrin wọn. Òun ni ó jẹ́ olókìkí jùlọ ninu “Àwọn Ọgbọ̀n Akọni,” ó sì di aṣiwaju wọn, ṣugbọn kò lókìkí tó “Àwọn Akọni Mẹta” àkọ́kọ́. Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, ará Kabiseeli, náà tún jẹ́ akọni ọmọ ogun, ọpọlọpọ nǹkan ńláńlá ni ó fi ìgboyà ṣe. Ó pa àwọn akikanju ọmọ ogun ará Moabu meji ní àkókò kan. Ní ọjọ́ kan lẹ́yìn tí yìnyín bọ́ sílẹ̀, ó wọ inú ihò kan lọ, ó sì pa kinniun kan sibẹ. Bẹ́ẹ̀ náà ni, ó pa ọkunrin ará Ijipti kan tí ó ṣígbọnlẹ̀, tí ó sì dira ogun tòun tọ̀kọ̀. Kùmọ̀ lásán ni Bẹnaya mú lọ́wọ́ tí ó fi dojú kọ ọ́, ó já ọ̀kọ̀ tí ó wà lọ́wọ́ ọmọ ogun ará Ijipti yìí gbà, ó sì fi pa á. Àwọn nǹkan akikanju ti Bẹnaya ṣe nìwọ̀nyí, ó sì ní òkìkí, yàtọ̀ sí ti “Àwọn Akọni Mẹta”. Akọni ni láàrin “Àwọn Ọgbọ̀n Akọni”, ṣugbọn kò lókìkí tó “Àwọn Akọni Mẹta” ti àkọ́kọ́, òun ni Dafidi sì fi ṣe olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀. Àwọn mìíràn tí wọ́n tún jẹ́ ara “Àwọn Ọgbọ̀n Akọni” náà nìwọ̀nyí: Asaheli arakunrin Joabu, ati Elihanani, ọmọ Dodo, ará Bẹtilẹhẹmu. Ṣama ati Elika, àwọn mejeeji jẹ́ ará Harodu; Helesi, ará Paliti, Ira, ọmọ Ikeṣi, ará Tekoa; Abieseri, ará Anatoti, ati Mebunai, ará Huṣa; Salimoni, ará Ahohi, ati Maharai, ará Netofa; Helebu, ọmọ Baana, tí òun náà jẹ́ ará Netofa, ati Itai, ọmọ Ribai, ará Gibea, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini; Bẹnaya ará Piratoni ati Hidai ará ẹ̀bá àwọn odò Gaaṣi; Abialiboni ará Araba, ati Asimafeti ará Bahurimu; Eliaba, ará Ṣaaliboni, àwọn ọmọ Jaṣeni, ati Jonatani; Ṣama, ará Harari, Ahiamu, ọmọ Ṣarari, ará Harari; Elifeleti, ọmọ Ahasibai, ará Maaka, Eliamu, ọmọ Ahitofẹli, ará Gilo; Hesiro, ará Kamẹli, Paarai, ará Abiti; Igali, ọmọ Natani, ará Soba, Bani, ará Gadi; Seleki, ará Amoni, Naharai, ará Beeroti, tí ó máa ń ru ihamọra Joabu, ọmọ Seruaya. Ira ati Garebu, àwọn mejeeji jẹ́ ará Itiri; ati Uraya, ará Hiti. Gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ akọni ọmọ ogun náà jẹ́ mẹtadinlogoji. Inú tún bí OLUWA sí àwọn ọmọ Israẹli, ó sì ti Dafidi láti kó ìyọnu bá wọn. OLUWA wí fún un pé, lọ ka àwọn ọmọ Israẹli ati ti Juda. Dafidi bá pàṣẹ fún Joabu, ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀, tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, ó ní, “Ẹ lọ sí gbogbo ẹ̀yà Israẹli, láti Dani títí dé Beeriṣeba, kí ẹ sì ka gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà níbẹ̀, kí n lè mọ iye wọn.” Ṣugbọn Joabu bi ọba léèrè pé, “Kí OLUWA Ọlọrun rẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli pọ̀ jù báyìí lọ, ní ìlọ́po ọ̀nà ọgọrun-un (100), nígbà tí oluwa mi ṣì wà láàyè; ṣugbọn, kí ló dé tí kabiyesi fi fẹ́ ka àwọn eniyan wọnyi?” Ṣugbọn àṣẹ tí ọba pa ni ó borí. Ni Joabu ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀ bá jáde kúrò níwájú ọba, wọ́n bá lọ ka àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n ré odò Jọdani kọjá, wọ́n pàgọ́ sí ìhà gúsù Aroeri, ìlú tí ó wà ní ààrin àfonífojì, ní agbègbè Gadi. Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti lọ sí ìhà àríwá, títí dé Jaseri. Wọ́n lọ sí Gileadi, ati sí Kadeṣi ní ilẹ̀ àwọn ará Hiti. Lẹ́yìn náà, wọ́n lọ sí Dani. Láti Dani, wọ́n lọ sí apá ìwọ̀ oòrùn títí dé Sidoni. Lẹ́yìn náà, wọ́n lọ sí apá gúsù. Wọ́n dé ìlú olódi ti Tire, títí lọ dé gbogbo ìlú àwọn ará Hifi, ati ti àwọn ará Kenaani. Níkẹyìn, wọ́n wá sí Beeriṣeba ní apá ìhà gúsù Juda. Oṣù mẹsan-an ati ogúnjọ́ ni ó gbà wọ́n láti lọ káàkiri gbogbo ilẹ̀ Israẹli, lẹ́yìn náà, wọ́n pada sí Jerusalẹmu. Joabu sọ iye àwọn eniyan tí ó kà fún ọba: Ogoji ọ̀kẹ́ (800,000) ni àwọn ọkunrin tí wọ́n tó ogun jà ní ilẹ̀ Israẹli, àwọn ti ilẹ̀ Juda sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹẹdọgbọn (500,000). Ṣugbọn lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi ka àwọn eniyan náà tán, ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí dà á láàmú. Ó bá wí fún OLUWA pé, “Ohun tí mo ṣe yìí burú gan-an, ẹ̀ṣẹ̀ ńlá gbáà ni. Jọ̀wọ́, dáríjì èmi iranṣẹ rẹ, ìwà òmùgọ̀ gbáà ni mo hù.” Nígbà tí Dafidi jí ní òwúrọ̀, OLUWA rán wolii Gadi, aríran rẹ̀ sí i pé, “Lọ sọ fún Dafidi pé mo fi nǹkan mẹta siwaju rẹ̀; kí ó yan ọ̀kan tí ó fẹ́ kí n ṣe sí òun ninu mẹtẹẹta.” Gadi bá lọ sọ ohun tí OLUWA wí fún Dafidi. Ó bèèrè pé, “Èwo ni o fẹ́ yàn ninu mẹtẹẹta yìí, ekinni, kí ìyàn mú ní ilẹ̀ rẹ fún ọdún mẹta; ekeji, kí o máa sá fún àwọn ọ̀tá rẹ fún oṣù mẹta; ẹkẹta, kí àjàkálẹ̀ àrùn jà fún ọjọ́ mẹta ní gbogbo ilẹ̀ rẹ? Rò ó dáradára, kí o sì sọ èyí tí o fẹ́, kí n lọ sọ fún OLUWA.” Dafidi dá Gadi lóhùn pé, “Ìdààmú ńlá ni ó dé bá mi yìí, ṣugbọn ó yá mi lára kí OLUWA jẹ wá níyà ju pé kí ó fi mí lé eniyan lọ́wọ́ lọ; nítorí pé, aláàánú ni OLUWA.” Nítorí náà, OLUWA fi àjàkálẹ̀ àrùn bá Israẹli jà. Ó bẹ̀rẹ̀ láti òwúrọ̀ títí di àkókò tí ó yàn jákèjádò ilẹ̀ Israẹli. Láti Dani títí dé Beeriṣeba, gbogbo àwọn tí ó kú jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹta ati ẹgbaarun (70,000). Nígbà tí angẹli OLUWA náà fẹ́ bẹ̀rẹ̀ láti máa pa Jerusalẹmu run, OLUWA yí ọkàn pada nípa jíjẹ tí ó ń jẹ àwọn eniyan náà níyà. Ó bá wí fún angẹli náà pé, “Ó tó gẹ́ẹ́, dáwọ́ dúró.” Níbi ìpakà Arauna ará Jebusi kan ni angẹli náà wà nígbà náà. Nígbà tí Dafidi rí angẹli tí ó ń pa àwọn eniyan náà, ó wí fún OLUWA pé, “Èmi ni mo ṣẹ̀, èmi ni mo ṣe burúkú. Kí ni àwọn eniyan wọnyi ṣe? Èmi ati ìdílé baba mi ni ó yẹ kí ó jẹ níyà.” Ní ọjọ́ náà gan-an, Gadi tọ Dafidi lọ, ó sì wí fún un pé, “Lọ sí ibi ìpakà Arauna kí o sì tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA níbẹ̀.” Dafidi pa àṣẹ OLUWA mọ́, ó sì lọ sí ibi ìpakà Arauna, gẹ́gẹ́ bí Gadi ti sọ fún un. Nígbà tí Arauna wo ìsàlẹ̀, ó rí ọba ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí wọn ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó lọ pàdé rẹ̀, ó kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó sì dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó bi í pé, “Ṣé kò sí, tí oluwa mi, ọba, fi wá sọ́dọ̀ èmi, iranṣẹ rẹ̀?” Dafidi dá a lóhùn pé, “Ilẹ̀ ìpakà rẹ ni mo fẹ́ rà, mo fẹ́ tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA, kí àjàkálẹ̀ àrùn yìí lè dáwọ́ dúró.” Arauna dá a lóhùn pé, “Máa mú un, kí o sì mú ohunkohun tí o bá fẹ́ fi rúbọ sí OLUWA. Akọ mààlúù nìwọ̀nyí, tí o lè fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA. Àwọn àjàgà wọn nìwọ̀nyí, ati àwọn igi ìpakà tí o lè lò fún igi ìdáná.” Arauna kó gbogbo rẹ̀ fún ọba, ó ní, “Kí OLUWA Ọlọrun rẹ gba ẹbọ náà.” Ṣugbọn ọba dá a lóhùn pé, “Rárá o, n óo san owó rẹ̀ fún ọ, nítorí pé ohunkohun tí kò bá ní ná mi lówó, n kò ní fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun mi.” Dafidi bá ra ibi ìpakà ati àwọn akọ mààlúù náà, ní aadọta ṣekeli owó fadaka. Ó kọ́ pẹpẹ kan sibẹ fún OLUWA, ó sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia. OLUWA gbọ́ adura rẹ̀ lórí ilẹ̀ náà, àjàkálẹ̀ àrùn náà sì dáwọ́ dúró ní ilẹ̀ Israẹli. Ní àkókò yìí, Dafidi ọba ti di arúgbó. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé aṣọ tí ó nípọn ni wọ́n fi ń bò ó, òtútù a tún máa mú un. Nítorí náà, àwọn iranṣẹ rẹ̀ wí fún un pé, “Kabiyesi, jẹ́ kí á wá ọdọmọbinrin kan fún ọ, tí yóo máa wà pẹlu rẹ, tí yóo sì máa tọ́jú rẹ. Yóo máa sùn tì ọ́ kí ara rẹ lè máa móoru.” Nítorí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá ọdọmọbinrin tí ó lẹ́wà gidigidi ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli. Wọ́n rí ọdọmọbinrin arẹwà kan ní ìlú Ṣunemu, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Abiṣagi, wọ́n sì mú un tọ Dafidi wá. Ọdọmọbinrin náà dára gan-an; ó wà lọ́dọ̀ ọba, ó ń tọ́jú rẹ̀, ṣugbọn ọba kò bá a lòpọ̀ rárá. Adonija, ọmọ tí Hagiti bí fún Dafidi, bẹ̀rẹ̀ sí gbéraga, ó ń wí pé, “Èmi ni n óo jọba.” Ó bá lọ tọ́jú kẹ̀kẹ́ ogun, ati àwọn ẹlẹ́ṣin ati aadọta ọkunrin tí yóo máa sáré níwájú rẹ̀. Adonija yìí ni wọ́n bí tẹ̀lé Absalomu, ó jẹ́ arẹwà ọkunrin; baba rẹ̀ kò sì fi ìgbà kan dojú kọ ọ́ kí ó bá a wí nítorí ohunkohun rí. Adonija lọ jíròrò pẹlu Joabu, ọmọ Seruaya, ati Abiatari alufaa, àwọn mejeeji tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ràn án lọ́wọ́. Ṣugbọn Sadoku alufaa, ati Bẹnaya ọmọ Jehoiada, ati Natani wolii, ati Ṣimei, Rei, ati àwọn akọni Dafidi kò faramọ́ ohun tí Adonija ṣe, wọn kò sì sí lẹ́yìn rẹ̀. Ní ọjọ́ kan, Adonija fi ọpọlọpọ aguntan, pẹlu akọ mààlúù, ati àbọ́pa mààlúù rúbọ níbi Àpáta Ejò, lẹ́bàá orísun Enrogeli, ó sì pe àwọn ọmọ ọba yòókù, àwọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ọba ní ilẹ̀ Juda. Ṣugbọn kò pe Natani wolii, tabi Bẹnaya, tabi àwọn akọni ninu àwọn jagunjagun ọba, tabi Solomoni, arakunrin rẹ̀. Natani bá tọ Batiṣeba ìyá Solomoni lọ, ó bi í pé, “Ṣé o ti gbọ́ pé Adonija ọmọ Hagiti ti fi ara rẹ̀ jọba, Dafidi ọba kò sì mọ nǹkankan nípa rẹ̀. Wá, jẹ́ kí n gbà ọ́ nímọ̀ràn kan, bí o bá fẹ́ràn ẹ̀mí rẹ, ati ẹ̀mí Solomoni, ọmọ rẹ. Tọ Dafidi ọba lọ lẹsẹkẹsẹ, kí o sì bi í pé, ṣebí òun ni ó fi ìbúra ṣe ìlérí fún ọ pé Solomoni ọmọ rẹ ni yóo jọba lẹ́yìn rẹ̀? Kí ló dé tí Adonija fi di ọba? Bí o bá ti ń bá ọba sọ̀rọ̀ ni n óo wọlé, n óo sì sọ pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” Batiṣeba bá wọlé tọ ọba lọ ninu yàrá rẹ̀. (Ọba ti di arúgbó ní àkókò yìí, Abiṣagi ará Ṣunemu ni ó ń tọ́jú rẹ̀.) Batiṣeba wólẹ̀ níwájú ọba, ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Ọba bá bi í pé, “Kí ni o fẹ́ gbà?” Ó dá ọba lóhùn, ó ní, “Kabiyesi, ìwọ ni o ṣe ìlérí fún èmi iranṣẹbinrin rẹ, tí o sì fi orúkọ OLUWA Ọlọrun rẹ búra pé, Solomoni ọmọ mi ni yóo jọba lẹ́yìn rẹ. Ṣugbọn Adonija ti fi ara rẹ̀ jọba, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kabiyesi kò mọ nǹkankan nípa rẹ̀. Ó ti fi ọpọlọpọ akọ mààlúù, ati aguntan, ati àbọ́pa mààlúù rúbọ. Ó pe gbogbo àwọn ọmọ ọba lọkunrin, ati Abiatari alufaa, ati Joabu balogun rẹ síbi àsè rẹ̀, ṣugbọn kò pe Solomoni, iranṣẹ rẹ. Ojú rẹ ni gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ń wò báyìí, pé kí o fa ẹni tí o bá fẹ́ kí ó jọba lẹ́yìn rẹ kalẹ̀ fún wọn. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbàrà tí kabiyesi bá ti kú tán, bí wọ́n ti ń ṣe àwọn arúfin ni wọn yóo ṣe èmi ati Solomoni ọmọ rẹ.” Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni Natani wolii wọlé. Wọ́n bá sọ fún ọba pé Natani wolii ti dé. Nígbà tí Natani wọlé, ó wólẹ̀ níwájú ọba, ó sì dojúbolẹ̀. Ó wí pé, “Kabiyesi, ṣé o ti kéde pé Adonija ni yóo jọba lẹ́yìn rẹ ni? Ní òní olónìí yìí, ó ti fi ọpọlọpọ akọ mààlúù, ati aguntan, ati àbọ́pa mààlúù rúbọ. Ó pe gbogbo àwọn ọmọ ọba lọkunrin, ati Joabu balogun, ati Abiatari, alufaa. Bí mo ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí, gbogbo wọn wà níbi tí wọ́n ti ń jẹ, tí wọn ń mu, tí wọn ń pariwo pé, ‘Kí Adonija ọba kí ó pẹ́.’ Ṣugbọn kò pe èmi iranṣẹ rẹ sí ibi àsè náà, kò sì pe Sadoku alufaa, tabi Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, tabi Solomoni iranṣẹ rẹ. Ǹjẹ́ kabiyesi ha lè lọ́wọ́ sí irú nǹkan báyìí; kí ó má tilẹ̀ sọ ẹni tí yóo gun orí oyè lẹ́yìn rẹ̀ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀?” Dafidi ọba bá ní kí wọ́n pe Batiṣeba pada wọlé. Ó bá pada wá siwaju ọba. Ọba bá búra fún un pé, “Mo ṣe ìlérí fún ọ ní orúkọ OLUWA Alààyè, tí ó gbà mí ninu gbogbo ìyọnu mi, pé lónìí ni n óo mú ìbúra tí mo búra fún ọ ní orúkọ OLUWA Ọlọrun Israẹli ṣẹ, pé, Solomoni, ọmọ rẹ ni yóo jọba lẹ́yìn mi.” Batiṣeba wólẹ̀ níwájú ọba, ó dojúbolẹ̀, ó ní, “Kabiyesi, oluwa mi, kí ẹ̀mí ọba ó gùn.” Ọba bá ranṣẹ pe Sadoku, alufaa, ati Natani wolii, ati Bẹnaya ọmọ Jehoiada, gbogbo wọ́n sì pésẹ̀ sọ́dọ̀ ọba. Ọba bá pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ kó gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ mi lẹ́yìn, kí ẹ sì gbé Solomoni gun ìbaaka mi, kí ẹ mú un lọ sí odò Gihoni, kí Sadoku, alufaa ati Natani wolii, fi àmì òróró yàn án ní ọba níbẹ̀, lórí gbogbo Israẹli. Lẹ́yìn náà, kí ẹ fọn fèrè, kí ẹ sì hó pé, ‘Kí ẹ̀mí Solomoni, ọba, kí ó gùn!’ Lẹ́yìn náà, ẹ óo tẹ̀lé e pada wá síhìn-ín kí ó wá jókòó lórí ìtẹ́ mi; nítorí pé òun ni yóo jọba lẹ́yìn mi. Òun ni mo yàn láti jọba Israẹli ati Juda.” Bẹnaya bá dáhùn pé, “Àṣẹ! Kí OLUWA Ọlọrun rẹ bá wa lọ́wọ́ sí i. Bí OLUWA ti wà pẹlu kabiyesi, bẹ́ẹ̀ náà ni kí ó wà pẹlu Solomoni, kí ó sì mú kí ìgbà tirẹ̀ tún dára ju ìgbà ti kabiyesi, oluwa mi, Dafidi ọba lọ.” Sadoku alufaa, ati Natani wolii, ati Bẹnaya, pẹlu àwọn ará Kereti ati àwọn ará Peleti tí wọn ń ṣọ́ ọba, bá gbé Solomoni gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Dafidi ọba, wọ́n sì mú un lọ sí odò Gihoni. Sadoku alufaa, bá mú ìwo tí wọ́n rọ òróró olifi sí, tí ó ti mú láti inú àgọ́ OLUWA jáde, ó sì ta òróró náà sí Solomoni lórí. Wọ́n fọn fèrè, gbogbo wọn sì hó pé, “Kí Solomoni, ọba, kí ó pẹ́.” Gbogbo eniyan bá tẹ̀lé e pada, wọ́n ń fọn fèrè, wọ́n ń hó fún ayọ̀. Ariwo tí wọn ń pa pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ fi mì tìtì. Bí Adonija ati gbogbo àwọn tí ó pè sí ibi àsè rẹ̀ ti ń parí àsè, wọ́n gbọ́ ariwo náà. Nígbà tí Joabu gbọ́ fèrè, ó bèèrè pé, “Kí ni ìtumọ̀ gbogbo ariwo tí wọn ń pa ninu ìlú yìí?” Kí ó tó dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ, Jonatani, ọmọ Abiatari, alufaa, dé. Adonija sọ fún un pé, “Máa wọlé bọ̀; eniyan rere ni ìwọ, ó sì níláti jẹ́ pé ìròyìn rere ni ò ń mú bọ̀.” Jonatani bá dáhùn pé, “Rárá o, kabiyesi ti fi Solomoni jọba! Ó sì ti rán Sadoku alufaa, ati Natani wolii, ati Bẹnaya ati àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba pé kí wọ́n tẹ̀lé Solomoni, wọ́n sì ti gbé e gun orí ìbaaka ọba. Sadoku alufaa ati Natani wolii sì ti fi àmì òróró yàn án ní ọba ní odò Gihoni. Lẹ́yìn náà, wọ́n ti pada lọ sí ààrin ìlú, wọ́n sì ń hó fún ayọ̀. Ariwo sì ti gba gbogbo ìlú. Ìdí rẹ̀ ni ẹ fi ń gbọ́ ariwo. Solomoni ti gúnwà lórí ìtẹ́ ọba. Kí ló tún kù! Gbogbo àwọn iranṣẹ ọba ni wọ́n ti lọ kí Dafidi ọba, pé, ‘Kí Ọlọrun rẹ mú kí Solomoni lókìkí jù ọ́ lọ, kí ìjọba rẹ̀ sì ju tìrẹ lọ.’ Ọba bá tẹríba, ó sì sin Ọlọrun lórí ibùsùn rẹ̀, ó ní ‘Ìyìn ni fún OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí ó jẹ́ kí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ mi jọba lónìí, tí ó sì jẹ́ kí n fi ojú mi rí i.’ ” Ẹ̀rù ba gbogbo àwọn tí wọ́n lọ bá Adonija jẹ àsè, gbogbo wọ́n bá dìde, olukuluku bá tirẹ̀ lọ. Ẹ̀rù Solomoni ba Adonija tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi sá lọ sinu Àgọ́ OLUWA, tí ó sì di ìwo pẹpẹ mú. Wọ́n sọ fún Solomoni ọba pé ẹ̀rù rẹ ń ba Adonija ati pé ó wà níbi tí ó ti di ìwo pẹpẹ mú, tí ó sì wí pé, àfi kí Solomoni ọba fi ìbúra ṣèlérí pé kò ní pa òun. Solomoni dáhùn pé, “Bí ó bá jẹ́ olóòótọ́, ẹnikẹ́ni kò ní fi ọwọ́ kan ẹyọ kan ninu irun orí rẹ̀, ṣugbọn bí ó bá hùwà ọ̀tẹ̀, yóo kú.” Solomoni ọba bá ranṣẹ lọ mú Adonija wá láti ibi pẹpẹ. Adonija lọ siwaju ọba, ó sì wólẹ̀. Ọba sọ fún un pé kí ó máa lọ sí ilé rẹ̀. Nígbà tí ó kù dẹ̀dẹ̀ kí Dafidi jáde láyé, ó pe Solomoni, ọmọ rẹ̀, ó sì kìlọ̀ fún un pé, “Ó tó àkókò fún mi, láti lọ sí ibi tí àgbà ń rè. Mú ọkàn gírí kí o sì ṣe bí ọkunrin. Ṣe gbogbo ohun tí OLUWA Ọlọrun rẹ pa láṣẹ fún ọ pé kí o ṣe, máa tẹ̀lé ọ̀nà rẹ̀, sì pa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀ mọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ ọ sinu ìwé òfin Mose, kí gbogbo ohun tí o bá ń ṣe lè máa yọrí sí rere, níbikíbi tí o bá n lọ. Bí o bá ń gbọ́ ti OLUWA, OLUWA yóo pa ìlérí tí ó ṣe nípa mi mọ́, pé arọmọdọmọ mi ni yóo máa jọba ní Israẹli níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá pa òfin òun mọ tọkàntọkàn, pẹlu òtítọ́ inú. “Siwaju sí i, ranti ohun tí Joabu ọmọ Seruaya ṣe sí mi, tí ó pa àwọn ọ̀gágun Israẹli meji: Abineri ọmọ Neri ati Amasa ọmọ Jeteri. Ranti pé ní àkókò tí kò sí ogun ni ó pa wọ́n; tí ó fi gbẹ̀san ikú ẹni tí wọ́n pa ní àkókò ogun. Pípa tí ó pa àwọn aláìṣẹ̀ wọnyi, ọrùn mi ni ó pa wọ́n sí, ẹrù ẹ̀bi wọn sì wà lórí mi. Ìwọ náà mọ ohun tí ó yẹ kí o ṣe gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n ọmọ, ṣugbọn o kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó fi ọwọ́ rọrí kú. “Ṣugbọn òtítọ́ inú ni kí o máa fi bá àwọn ọmọ Basilai ará Gileadi lò. Jẹ́ kí wọ́n wà lára àwọn tí yóo máa bá ọ jẹun pọ̀, nítorí pé òótọ́ inú ni wọ́n fi wá pàdé mi ní àkókò tí mò ń sá lọ fún Absalomu, arakunrin rẹ. “Bẹ́ẹ̀ náà sì ni Ṣimei ọmọ Gera ará Bahurimu láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, èpè burúkú ni ó ń gbé mi ṣẹ́ lemọ́lemọ́ ní ọjọ́ tí mo lọ sí Mahanaimu. Ṣugbọn nígbà tí ó wá pàdé mi létí odò Jọdani, mo jẹ́jẹ̀ẹ́ fún un ní orúkọ OLUWA pé, n kò ní pa á. Ṣugbọn o kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó lọ láìjìyà. Ìwọ náà mọ ohun tí ó yẹ kí o ṣe gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n ọmọ, o kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó fi ọwọ́ rọrí kú.” Kò pẹ́ pupọ lẹ́yìn náà, Dafidi, ọba kú, wọ́n sì sin ín sí ìlú Dafidi. Ogoji ọdún ni ó fi jọba Israẹli. Ó ṣe ọdún meje lórí oyè ní Heburoni, ó sì ṣe ọdún mẹtalelọgbọn ní Jerusalẹmu. Solomoni gorí oyè lẹ́yìn ikú baba rẹ̀, ìjọba rẹ̀ sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ gbọningbọnin. Ní ọjọ́ kan, Adonija ọmọ Hagiti, lọ sí ọ̀dọ̀ Batiṣeba, ìyá Solomoni. Batiṣeba bá bèèrè pé, “Ṣé alaafia ni o?” Adonija dá a lóhùn pé, “Alaafia ni, kinní kan ni mo fẹ́ bá ọ sọ.” Batiṣeba bi í pé, “Kí ni?” Ó bá dá Batiṣeba lóhùn pé, “Ṣé o mọ̀ pé èmi ni ó yẹ kí n jọba, ati pé gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n lérò pé èmi ni n óo jọba. Ṣugbọn kò rí bẹ́ẹ̀, arakunrin mi ló jọba, nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni ó wu OLUWA. Kinní kan ni mo wá fẹ́ tọrọ, jọ̀wọ́, má fi kinní ọ̀hún dù mí.” Batiṣeba bá bi í pé, “Kí ni nǹkan náà?” Ó bá dá Batiṣeba lóhùn, ó ní, “Jọ̀wọ́ bá mi bẹ Solomoni ọba, kí ó fún mi ní Abiṣagi, ará Ṣunemu, kí n fi ṣe aya. Mo mọ̀ pé kò ní kọ̀ sí ọ lẹ́nu.” Batiṣeba bá dá a lóhùn pé, “Ó dára, n óo bá ọba sọ̀rọ̀.” Batiṣeba bá lọ sọ́dọ̀ ọba láti jíṣẹ́ Adonija fún un. Bí ó ti wọlé, ọba dìde, ó tẹríba fún ìyá rẹ̀, ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó bá tún jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀, ó ní kí wọ́n gbé ìjókòó kan wá, ìyá rẹ̀ sì jókòó ní apá ọ̀tún rẹ̀. Batiṣeba wí fún Solomoni pé, “Nǹkan kékeré kan ni mo fẹ́ tọrọ lọ́wọ́ rẹ, jọ̀wọ́, má fi ohun náà dù mi.” Ọba bèèrè pé, “Kí ni, ìyá mi?” Ó sì fi kún un pé òun kò ní fi dù ú. Batiṣeba dá a lóhùn pé, “Fi Abiṣagi, ará Ṣunemu fún Adonija arakunrin rẹ, kí ó fi ṣe aya.” Ọba bá bi ìyá rẹ̀ pé, “Kí ló dé tí o fi ní kí n fún un ní Abiṣagi nìkan? Ò bá kúkú ní kí n dìde fún un lórí ìtẹ́ tí mo wà yìí. Ṣebí òun ni ẹ̀gbọ́n mi, ẹ̀yìn rẹ̀ sì ni Abiatari alufaa ati Joabu ọmọ Seruaya wà.” Solomoni bá búra lórúkọ OLUWA pé, kí Ọlọrun pa òun bí òun kò bá pa Adonija nítorí ọ̀rọ̀ yìí. Ó ní, “Mo fi orúkọ OLUWA alààyè búra, ẹni tí ó gbé mi ka orí ìtẹ́ Dafidi baba mi tí ó fi ìdí mi múlẹ̀, tí ó mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, tí ó sì fi ìjọba náà fún èmi ati arọmọdọmọ mi, lónìí olónìí ni Adonija yóo kú.” Solomoni ọba bá pàṣẹ fún Bẹnaya, pé kí ó lọ pa Adonija, ó bá jáde, ó sì lọ pa á. Lẹ́yìn náà, Solomoni ọba sọ fún Abiatari alufaa, pé, “Wá pada lọ sí orí ilẹ̀ rẹ ní Anatoti, pípa ni ó yẹ kí n pa ọ́, ṣugbọn n kò ní pa ọ́ nisinsinyii, nítorí pé ìwọ ni o jẹ́ alákòóso fún gbígbé Àpótí Ẹ̀rí káàkiri nígbà tí o wà pẹlu Dafidi, baba mi, o sì bá baba mi pín ninu gbogbo ìṣòro rẹ̀.” Solomoni bá yọ Abiatari kúrò ninu iṣẹ́ alufaa OLUWA tí ó ń ṣe, ó sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ ní Ṣilo ṣẹ, nípa Eli alufaa ati arọmọdọmọ rẹ̀. Nígbà tí Joabu gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó sá lọ sinu Àgọ́ OLUWA, ó sì di ìwo pẹpẹ mú, nítorí pé lẹ́yìn Adonija ni ó ti wà tẹ́lẹ̀ rí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí lẹ́yìn Absalomu. Nígbà tí Solomoni gbọ́ pé Joabu ti sá lọ sinu Àgọ́ OLUWA, ati pé ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ, Solomoni rán Bẹnaya kí ó lọ pa á. Bẹnaya bá lọ sinu Àgọ́ OLUWA, ó wí fún Joabu pé, “Ọba pàṣẹ pé kí o jáde.” Ṣugbọn Joabu dá a lóhùn, ó ní, “Rárá, níhìn-ín ni n óo kú sí.” Bẹnaya bá pada lọ sọ ohun tí Joabu wí fún ọba. Ọba dá a lóhùn pé, “Ṣe bí Joabu ti ní kí o ṣe. Pa á, kí o sì sin ín. Nígbà náà ni ọrùn èmi, ati arọmọdọmọ Dafidi yóo tó mọ́ kúrò ninu ohun tí Joabu ṣe nígbà tí ó pa àwọn aláìṣẹ̀. OLUWA yóo jẹ Joabu níyà fún àwọn eniyan tí ó pa láìjẹ́ pé Dafidi baba mí mọ ohunkohun nípa rẹ̀. Ó pa Abineri, ọmọ Neri, ọ̀gágun àwọn ọmọ ogun Israẹli ati Amasa, ọmọ Jeteri, ọ̀gágun àwọn ọmọ ogun Juda. Àwọn mejeeji tí ó pa láìṣẹ̀ yìí ṣe olóòótọ́ ju òun pàápàá lọ. Ẹ̀jẹ̀ àwọn tí ó pa yóo wà lórí rẹ̀ ati lórí àwọn arọmọdọmọ rẹ̀ títí lae, ṣugbọn OLUWA yóo fún Dafidi ati àwọn arọmọdọmọ rẹ̀ ati ilé rẹ̀ ati ìjọba rẹ̀ ní alaafia títí lae.” Bẹnaya ọmọ Jehoiada bá lọ sinu Àgọ́ OLUWA, ó pa Joabu, wọn sì sin ín sinu ilé rẹ̀ ninu aṣálẹ̀. Ọba fi Bẹnaya jẹ balogun rẹ̀ dípò Joabu, ó sì fi Sadoku jẹ alufaa dípò Abiatari. Lẹ́yìn náà, ọba ranṣẹ pe Ṣimei, ó wí fún un pé, “Kọ́ ilé kan sí Jerusalẹmu níhìn-ín kí o sì máa gbé ibẹ̀. O kò gbọdọ̀ jáde lọ sí ibìkankan. Ọjọ́ tí o bá jáde kọjá odò Kidironi, pípa ni n óo pa ọ́, ẹ̀jẹ̀ rẹ yóo sì wà lórí ara rẹ.” Ṣimei dá a lóhùn, ó ní, “Gbogbo ohun tí o sọ ni ó dára, oluwa mi, bí o ti wí ni èmi iranṣẹ rẹ yóo sì ṣe.” Ṣimei sì wà ní Jerusalẹmu fún ìgbà pípẹ́. Lẹ́yìn ọdún mẹta, àwọn ẹrú Ṣimei meji kan sá lọ sí ọ̀dọ̀ Akiṣi, ọmọ Maaka, ọba ìlú Gati. Nígbà tí Ṣimei gbọ́ pé àwọn ẹrú rẹ̀ yìí wà ní Gati, ó di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ kan ní gàárì, ó sì tọ Akiṣi ọba lọ sí ìlú Gati láti lọ wá àwọn ẹrú rẹ̀. Ó rí wọn, ó sì mú àwọn mejeeji pada wá sí ilé. Nígbà tí Solomoni gbọ́ pé Ṣimei ti kúrò ní Jerusalẹmu, ó ti lọ sí Gati, ó sì ti pada, ó ranṣẹ pè é, ó bi í pé, “Ṣebí o búra fún mi ní orúkọ OLUWA pé o kò ní jáde kúrò ní Jerusalẹmu? Mo sì kìlọ̀ fún ọ pé, ní ọjọ́ tí o bá jáde, pípa ni n óo pa ọ́. O gbà bẹ́ẹ̀, o sì ṣèlérí fún mi pé o óo pa òfin náà mọ́. Kí ló dé tí o kò mú ìlérí rẹ fún OLUWA ṣẹ, tí o sì rú òfin mi?” Dájúdájú o mọ gbogbo ibi tí o ṣe sí Dafidi, baba mi; OLUWA yóo jẹ ọ́ níyà ohun tí o ṣe. Ṣugbọn OLUWA yóo bukun mi, yóo sì fi ẹsẹ̀ ìjọba Dafidi múlẹ̀ títí lae. Solomoni ọba bá pàṣẹ fún Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, pé kí ó lọ pa Ṣimei; Bẹnaya bá jáde lọ, ó sì pa á. Lẹ́yìn náà ni gbogbo ìjọba Solomoni ọba wá wà ní ìkáwọ́ rẹ̀. Solomoni gbé ọmọ Farao, ọba Ijipti níyàwó, ó fi bá ọba Farao dá majẹmu àjọṣepọ̀ láàrin wọn. Solomoni mú iyawo náà wá sí ìlú Dafidi títí tí ó fi parí ààfin rẹ̀ ati ilé OLUWA tí ó ń kọ́, ati odi Jerusalẹmu tí ó ń mọ lọ́wọ́. Oríṣìíríṣìí pẹpẹ ìrúbọ ni àwọn eniyan tẹ́ káàkiri, tí wọ́n sì ń rúbọ lórí wọn, nítorí wọn kò tí ì kọ́ ilé OLUWA nígbà náà. Solomoni fẹ́ràn OLUWA, ó sì ń tẹ̀lé ìlànà Dafidi, baba rẹ̀, ṣugbọn òun náà a máa rúbọ, a sì máa sun turari lórí àwọn pẹpẹ ìrúbọ. Ọba a máa lọ sí Gibeoni láti rúbọ, nítorí pé níbẹ̀ ni pẹpẹ tí ó lókìkí jùlọ nígbà náà wà. A máa fi ẹgbẹrun (1,000) ẹran rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ náà. OLUWA fara han Solomoni ní ojú àlá ní òru ọjọ́ kan ní Gibeoni, ó sì bi í pé, “Kí ni o fẹ́ kí n fún ọ?” Solomoni dá OLUWA lóhùn, ó ní: “O ti fi ìfẹ́ ńlá rẹ, tí kìí yẹ̀ hàn sí Dafidi, baba mi, iranṣẹ rẹ, nítorí pé ó bá ọ lò pẹlu òtítọ́, òdodo ati ọkàn dídúró ṣinṣin. O sì ti fi ìfẹ́ ńlá tí kì í yẹ̀ yìí hàn sí i, o fún un ní ọmọ tí ó jọba lẹ́yìn rẹ̀ lónìí. Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun mi, ìwọ ni o jẹ́ kí èmi iranṣẹ rẹ gun orí oyè lẹ́yìn baba mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọde ni mí, n kò sì mọ̀ bí wọ́n ti ń ṣe àkóso. O sì fi èmi iranṣẹ rẹ sí ààrin àwọn eniyan tí o ti yàn fún ara rẹ, àwọn tí wọ́n pọ̀, tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò lóǹkà. Nítorí náà, OLUWA, fún èmi iranṣẹ rẹ ní ọgbọ́n láti darí àwọn eniyan rẹ, kí n lè mọ ìyàtọ̀ láàrin ire ati ibi, nítorí pé, bí kò bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ta ni lè ṣe àkóso àwọn eniyan rẹ tí wọ́n pọ̀ báyìí?” Inú OLUWA dùn fún ohun tí Solomoni bèèrè. Ọlọrun sì dá a lóhùn, ó ní, “Nítorí pé ọgbọ́n láti mọ ohun tí ó dára ni o bèèrè, tí o kò bèèrè ẹ̀mí gígùn, tabi ọpọlọpọ ọrọ̀ fún ara rẹ, tabi ẹ̀mí àwọn ọ̀tá rẹ, wò ó! N óo fún ọ ní ohun tí o bèèrè. Ọgbọ́n ati òye tí n óo fún ọ yóo tayọ ti gbogbo àwọn aṣiwaju rẹ, ati ti àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ. N óo fún ọ ní ohun tí o kò tilẹ̀ bèèrè. O óo ní ọrọ̀ ati ọlá tóbẹ́ẹ̀ tí kò ní sí ọba kan tí yóo dàbí rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. Bí o bá ń gbọ́ tèmi, tí o sì ń pa gbogbo àwọn òfin, ati àwọn ìlànà mi mọ́, gẹ́gẹ́ bí Dafidi, baba rẹ ti ṣe, n óo fún ọ ní ẹ̀mí gígùn pẹlu.” Nígbà tí Solomoni tají, ó rí i pé àlá ni òun ń lá, ó bá lọ sí Jerusalẹmu, ó lọ siwaju Àpótí Ẹ̀rí OLUWA, ó sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia sí OLUWA. Lẹ́yìn náà, ó se àsè ńlá fún gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀. Ní ọjọ́ kan, àwọn aṣẹ́wó meji kan kó ara wọn wá siwaju Solomoni ọba. Ọ̀kan ninu wọn ní, “Kabiyesi inú ilé kan náà ni èmi ati obinrin yìí ń gbé, ibẹ̀ ló sì wà nígbà tí mo fi bí ọmọkunrin kan. Ọjọ́ kẹta tí mo bí ọmọ tèmi ni obinrin yìí náà bí ọmọkunrin kan. Àwa meji péré ni a wà ninu ilé, kò sí ẹnìkẹta pẹlu wa. Ní alẹ́ ọjọ́ kan, ó sùn lé ọmọ tirẹ̀ mọ́lẹ̀, ọmọ tirẹ̀ bá kú. Ó bá dìde ní ọ̀gànjọ́ òru, ó wá jí ọmọ tèmi gbé ní ẹ̀gbẹ́ mi nígbà tí mo sùn lọ, ó tẹ́ ẹ sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀, ó sì tẹ́ òkú ọmọ tirẹ̀ sọ́dọ̀ mi. Nígbà tí mo jí ní ọjọ́ keji láti fún ọmọ ní oúnjẹ, mo rí i pé ó ti kú. Ṣugbọn nígbà tí mo yẹ̀ ẹ́ wò fínnífínní, mo rí i pé kì í ṣe ọmọ tèmi ni.” Ṣugbọn obinrin keji dáhùn pé, “Rárá! Èmi ni mo ni ààyè ọmọ, òkú ọmọ ni tìrẹ.” Ekinni náà tún dáhùn pé, “Irọ́ ni! Ìwọ ló ni òkú ọmọ, ààyè ọmọ ni tèmi.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí jiyàn níwájú ọba. Nígbà náà ni Solomoni ọba dáhùn, ó ní, “Ekinni keji yín ń wí pé, òun kọ́ ni òun ni òkú ọmọ, ààyè ni tòun.” Ọba bá ranṣẹ pé kí wọ́n mú idà kan wá. Nígbà tí wọ́n mú un dé, ó pàṣẹ pé kí wọ́n la ààyè ọmọ sí meji, kí wọ́n sì fún àwọn obinrin mejeeji ní ìdajì, ìdajì. Ọkàn ìyá tí ó ni ààyè ọmọ kò gbà á, nítorí ìfẹ́ tí ó ní sí ọmọ rẹ̀, ó wí fún ọba pé, “Kabiyesi, gbé ààyè ọmọ yìí fún ekeji mi, má pa á rárá.” Ṣugbọn èyí ekeji dáhùn pé, “Rárá! Kò ní jẹ́ tèmi, kò sì ní jẹ́ tìrẹ. Jẹ́ kí wọ́n là á sí meji.” Ọba dáhùn, ó ní, “Ẹ má pa ààyè ọmọ yìí rárá, ẹ gbé e fún obinrin àkọ́kọ́. Òun gan-an ni ìyá rẹ̀.” Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ irú ìdájọ́ tí Solomoni ọba dá yìí, ó mú kí ó túbọ̀ níyì lójú wọn; nítorí wọ́n mọ̀ pé Ọlọrun ni ó fún un ní ọgbọ́n láti ṣe ìdájọ́ ní irú ọ̀nà ẹ̀tọ́ bẹ́ẹ̀. Solomoni jọba gbogbo ilẹ̀ Israẹli, Orúkọ àwọn olórí ninu àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ nìwọ̀nyí: Asaraya, ọmọ Sadoku ni alufaa. Elihorefi ati Ahija, meji ninu àwọn ọmọ Ṣiṣa ni akọ̀wé ní ààfin ọba. Jehoṣafati, ọmọ Ahiludi ni olùtọ́jú àwọn ìwé àkọsílẹ̀. Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, ni balogun. Sadoku ati Abiatari jẹ́ alufaa, Asaraya, ọmọ Natani, ni olórí gbogbo àwọn òṣìṣẹ́. Sabudu, ọmọ Natani, ni alufaa ati olùdámọ̀ràn fún ọba. Ahiṣari ni olùdarí gbogbo àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ninu ààfin. Adoniramu ọmọ Abida ni olórí àwọn tí ń kó àwọn eniyan ṣiṣẹ́ tipátipá. Solomoni yan àwọn mejila gẹ́gẹ́ bí alákòóso ní ilẹ̀ Israẹli. Àwọn ni wọ́n ń ṣe ètò àtikó oúnjẹ jọ ní agbègbè wọn, fún ìtọ́jú ọba ati gbogbo àwọn tí ń gbé ààfin ọba. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn á máa pèsè oúnjẹ fún oṣù kọ̀ọ̀kan ninu ọdún kọ̀ọ̀kan. Orúkọ àwọn alákòóso mejeejila ati agbègbè tí olukuluku wọn ń mójú tó nìwọ̀nyí: Benhuri ní ń ṣe àkóso agbègbè olókè Efuraimu; Bẹndekeri ni alákòóso fún ìlú Makasi, ati Ṣaalibimu, ìlú Beti Ṣemeṣi, Eloni, ati Beti Hanani. Benhesedi ní Aruboti ni alákòóso fún ìlú Aruboti, ati Soko, ati gbogbo agbègbè Heferi. Bẹnabinadabu, ọkọ Tafati, ọmọ Solomoni, ni alákòóso gbogbo agbègbè Nafati-dori. Baana, ọmọ Ahiludi, ni alákòóso ìlú Taanaki, ati ti Megido, ati gbogbo agbègbè Beti Ṣeani, lẹ́bàá ìlú Saretani, ní ìhà gúsù Jesireeli ati Beti Ṣeani; títí dé ìlú Abeli Mehola títí dé òdìkejì Jokimeamu. Bẹngeberi ni alákòóso ìlú Ramoti Gileadi, (ati àwọn ìletò Jairi, ọmọ Manase, tí ó wà ní ilẹ̀ Gileadi, ati agbègbè Arigobu, ní ilẹ̀ Baṣani. Gbogbo wọn jẹ́ ọgọta ìlú ńláńlá tí wọn mọ odi yíká, bàbà ni wọ́n sì fi ṣe ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn ẹnubodè wọn.) Ahinadabu, ọmọ Ido ni alákòóso agbègbè Mahanaimu. Ahimaasi, (ọkọ Basemati, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Solomoni), ni alákòóso Nafutali. Baana, ọmọ Huṣai, ni alákòóso agbègbè Aṣeri, ati Bealoti. Jehoṣafati, ọmọ Parua, ni alákòóso agbègbè Isakari. Ṣimei, ọmọ Ela, ni alákòóso agbègbè Bẹnjamini. Geberi, ọmọ Uri, ni alákòóso agbègbè Gileadi, níbi tí Sihoni ọba àwọn ará Amori ati Ogu ọba Baṣani ti jọba tẹ́lẹ̀ rí. Lẹ́yìn àwọn alákòóso mejeejila wọnyi, alákòóso àgbà kan tún wà fún gbogbo ilẹ̀ Juda. Àwọn ọmọ Juda ati àwọn ọmọ Israẹli pọ̀ bíi yanrìn inú òkun, wọ́n ń rí jẹ, wọ́n ń rí mu, wọ́n sì láyọ̀. Solomoni jọba lórí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, láti odò Yufurate títí dé ilẹ̀ Filistia, títí dé ààlà ilẹ̀ àwọn ará Ijipti. Wọ́n ń san ìṣákọ́lẹ̀ fún un, wọ́n sì ń sìn ín ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. Àwọn nǹkan tí Solomoni ń lò fún ìtọ́jú oúnjẹ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nìwọ̀nyí: Ọgbọ̀n òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, ati ọgọta òṣùnwọ̀n ọkà tí wọ́n lọ̀; àbọ́pa mààlúù mẹ́wàá, ogún mààlúù tí wọn ń dà ninu pápá, ati ọgọrun-un aguntan; láìka àgbọ̀nrín, egbin, ìgalà, ati oríṣìíríṣìí ẹyẹ àbọ́pa. Solomoni jọba lórí gbogbo ilẹ̀ tí ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Yufurate, láti ìlú Tifisa, títí dé ìlú Gasa, ati lórí gbogbo àwọn ọba tí wọ́n wà ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Yufurate; alaafia sì wà láàrin òun ati àwọn agbègbè tí ó wà ní àyíká rẹ̀. Ní gbogbo àkókò Solomoni, gbogbo àwọn ọmọ Juda ati àwọn ọmọ Israẹli wà ní alaafia láti ìlú Dani títí dé Beeriṣeba. Ìdílé kọ̀ọ̀kan ní ọgbà àjàrà ati àwọn igi ọ̀pọ̀tọ́ tirẹ̀. Ọ̀kẹ́ meji (40,000) ni ilé tí Solomoni kọ́ fún àwọn ẹṣin tí ń fa àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó sì ní ẹgbaafa (12,000) eniyan tí ń gun ẹṣin. Alákòóso kọ̀ọ̀kan níí máa tọ́jú nǹkan jíjẹ tí Solomoni ọba ń lò fún ara rẹ̀ ati fún gbogbo àwọn tí ń jẹun ní ààfin rẹ̀; alákòóso kọ̀ọ̀kan sì ní oṣù tí ó gbọdọ̀ pèsè nǹkan jíjẹ, láìjẹ́ kí ohunkohun dín ninu ohun tí ọba nílò. Wọn a sì máa mú ọkà baali ati koríko wá fún àwọn ẹṣin tí ń wa kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹṣin tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́. Olukuluku a máa mú ohun tí wọ́n bù fún un wá sí ibi tí wọ́n ti nílò rẹ̀. Ọgbọ́n ati òye tí Ọlọrun fún Solomoni kọjá sísọ, ìmọ̀ rẹ̀ sì kọjá ìwọ̀n. Solomoni gbọ́n ju àwọn amòye ìhà ìlà oòrùn ati ti Ijipti lọ. Òun ni ó gbọ́n jùlọ ní gbogbo ayé. Ó gbọ́n ju Etani ará Ẹsira lọ, ati Hemani, ati Kakoli, ati Dada, àwọn ọmọ Maholi. Òkìkí rẹ̀ sì kàn káàkiri gbogbo agbègbè tí ó yí i ká. Ẹgbẹẹdogun (3,000) ni òwe tí òun nìkan pa, orin tí òun nìkan kọ sì jẹ́ marunlelẹgbẹrun. Ó sọ nípa igi, ó bẹ̀rẹ̀ láti orí igi kedari ti ilẹ̀ Lẹbanoni, títí kan Hisopu tí ó ń hù lára ògiri. Ó sọ nípa àwọn ẹranko, ati àwọn ẹyẹ, àwọn ohun tí ń fi àyà fà ati àwọn ẹja. Àwọn eniyan sì ń wá láti oniruuru orílẹ̀ èdè, ati láti ọ̀dọ̀ àwọn ọba ní gbogbo ayé, tí wọ́n ti gbúròó nípa ọgbọ́n rẹ̀, wọn á wá tẹ́tí sí ọgbọ́n rẹ̀. Nígbà tí Hiramu, ọba Tire, gbọ́ pé Solomoni ni ó gun orí oyè lẹ́yìn baba rẹ̀, ó rán oníṣẹ́ sí i; nítorí ọ̀rẹ́ ni òun ati Dafidi, wọ́n sì fẹ́ràn ara wọn. Solomoni náà ranṣẹ pada sí Hiramu, ó ní, “Ìwọ náà mọ̀ pé Dafidi, baba mi, kò lè kọ́ ilé ìsìn fún OLUWA Ọlọrun rẹ̀ nítorí gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ ni ó fi bá àwọn ọ̀tá rẹ̀ tí wọ́n yí i ká jagun, títí tí OLUWA fi fún un ní ìṣẹ́gun lórí wọn. Ṣugbọn nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun mi ti fún mi ní alaafia ní gbogbo agbègbè tí ó yí mi ká. N kò ní ọ̀tá kankan rárá, bẹ́ẹ̀ ni kò sí àjálù. Nisinsinyii, mo ti ṣe ìpinnu láti kọ́ ilé fún OLUWA Ọlọrun mi, gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀ sí Dafidi, baba mi, pé ọmọ rẹ̀, tí yóo gun orí oyè lẹ́yìn rẹ̀, ni yóo kọ́ ilé ìsìn fún òun. Nítorí náà, pàṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ, kí wọ́n bá mi gé igi kedari ní Lẹbanoni. Àwọn iranṣẹ mi yóo bá wọn ṣiṣẹ́ pọ̀, n óo sì san iyekíye tí o bá bèèrè fún owó iṣẹ́ wọn. Gẹ́gẹ́ bí ìwọ náà ti mọ̀, àwọn iranṣẹ mi kò mọ̀ bí a tií gé igi ìkọ́lé bí àwọn ará Sidoni.” Inú ọba Hiramu dùn pupọ nígbà tí wọ́n jíṣẹ́ Solomoni fún un. Ó ní, “Ẹni ìyìn ni OLUWA lónìí, nítorí pé ó fún Dafidi ní ọlọ́gbọ́n ọmọ, láti jọba lórí orílẹ̀-èdè ńlá yìí.” Ó ranṣẹ pada sí Solomoni, ó ní, “Mo gbọ́ iṣẹ́ tí o rán sí mi, n óo sì ṣe ohun tí o ní kí n ṣe fún ọ nípa igi kedari ati igi sipirẹsi. Àwọn iranṣẹ mi yóo gé igi náà ní Lẹbanoni, wọn yóo kó wọn wá sí etí òkun. Wọn óo dì wọ́n ní ìdì kọ̀ọ̀kan kí wọ́n lè tù wọ́n gba ojú òkun lọ sí ibikíbi tí o bá fẹ́. Wọn óo tú wọn kalẹ̀ níbẹ̀, wọn óo sì kó wọn fún àwọn iranṣẹ rẹ. Ohun tí mo fẹ́ kí o mójútó ni oúnjẹ tí èmi ati ìdílé mi óo máa jẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni Hiramu ṣe tọ́jú gbogbo igi kedari ati igi sipirẹsi tí Solomoni nílò fún un. Ní ọdọọdún, Solomoni a máa fún Hiramu ní ọ̀kẹ́ kan (20,000) òṣùnwọ̀n kori ọkà, ati ọ̀kẹ́ kan (20,000) òṣùnwọ̀n kori òróró dáradára fún ìtọ́jú oúnjẹ fún Hiramu ati àwọn eniyan rẹ̀. OLUWA fún Solomoni ní ọgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀, alaafia sì wà láàrin òun ati Hiramu, àwọn mejeeji sì bá ara wọn dá majẹmu. Solomoni ọba ṣa ẹgbaa mẹẹdogun (30,000) eniyan jọ lára àwọn ọmọ Israẹli, láti ṣe iṣẹ́ tipátipá. Ó fi Adoniramu ṣe alabojuto wọn. Ó pín wọn sí ọ̀nà mẹta: ẹgbaarun (10,000) ọkunrin ní ìpín kọ̀ọ̀kan. Ìpín kọ̀ọ̀kan a máa ṣiṣẹ́ fún oṣù kan ní Lẹbanoni, wọn á sì pada sílé fún oṣù meji. Solomoni sì tún ní ọ̀kẹ́ mẹrin (80,000) ọkunrin tí ń fọ́ òkúta ní agbègbè olókè; ati ọ̀kẹ́ mẹta ó lé ẹgbaarun (70,000) ọkunrin tí ń ru òkúta tí wọ́n bá fọ́. Ó yan ẹẹdẹgbaaji ó lé ọọdunrun (3,300) ọkunrin, láti máa bojútó iṣẹ́ àwọn òṣìṣẹ́. Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Solomoni ọba, wọ́n fọ́ òkúta ńláńlá, wọ́n sì gbẹ́ wọn fún mímọ ìpìlẹ̀ ilé OLUWA náà. Àwọn òṣìṣẹ́ Solomoni ati ti Hiramu, ati àwọn ọkunrin mìíràn láti ìlú Gebali ni wọ́n gbẹ́ òkúta, tí wọ́n sì la igi fún kíkọ́ ilé OLUWA. Nígbà tí ó di ọrinlenirinwo (480) ọdún tí àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, ní ọdún kẹrin tí Solomoni gun orí oyè ní Israẹli, ní oṣù Sifi, tíí ṣe oṣù keji ọdún náà, ni ó bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ilé OLUWA. Gígùn ilé tí Solomoni kọ́ fún OLUWA jẹ́ ọgọta igbọnwọ, ìbú rẹ̀ jẹ́ ogún igbọnwọ, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ. Yàrá àbáwọlé ilé ìsìn náà gùn ní ogún igbọnwọ, gígùn rẹ̀ ṣe déédé pẹlu ìbú rẹ̀, ó sì jìn sí ìsàlẹ̀ ní igbọnwọ mẹ́wàá níwájú. Ògiri ilé ìsìn náà ní àwọn fèrèsé tí wọ́n fẹ̀ ninu ju bí wọ́n ti fẹ̀ lóde lọ. Wọ́n kọ́ ilé alágbèékà mẹta mọ́ ara ògiri ilé ìsìn náà yípo lọ́wọ́ òde, ati gbọ̀ngàn ti òde, ati ibi mímọ́ ti inú; wọ́n sì kọ́ yàrá ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ sí i yípo. Gíga àgbékà kọ̀ọ̀kan ilé náà jẹ́ igbọnwọ marun-un; ilé ti ìsàlẹ̀ fẹ̀ ní igbọnwọ marun-un; àgbékà ti ààrin fẹ̀ ní igbọnwọ mẹfa, àgbékà ti òkè patapata fẹ̀ ní igbọnwọ meje. Ògiri àgbékà tí ó wà ní òkè patapata kò nípọn tó ti èyí tí ó wà ní ààrin, ti ààrin kò sì nípọn tó ti èyí tí ó wà ní ìsàlẹ̀ patapata; tí ó fi jẹ́ pé àwọn yàrá náà lè jókòó lórí ògiri láìfi òpó gbé wọn ró. Níbi tí wọ́n ti ń fọ́ òkúta ni wọ́n ti gbẹ́ gbogbo òkúta tí wọ́n fi kọ́ ilé ìsìn náà, wọn kò lo òòlù, tabi àáké, tabi ohun èlò irin kankan ninu tẹmpili náà nígbà tí wọ́n ti ń kọ́ ọ lọ. Ninu ilé alágbèékà mẹta tí wọ́n kọ́ mọ́ ara ilé ìsìn náà, ẹnu ọ̀nà ilé tí ó wà ní ìsàlẹ̀ patapata wà ní apá gúsù ilé ìsìn náà, ó ní àtẹ̀gùn tí ó lọ sí àgbékà keji, àgbékà keji sì ní àtẹ̀gùn tí ó lọ sí àgbékà kẹta. Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ọba ṣe kọ́ ilé ìsìn náà parí, ó sì fi ọ̀pá àjà ati pákó igi kedari ṣe àjà rẹ̀. Ara ògiri ilé ìsìn náà níta ni wọ́n kọ́ ilé alágbèékà mẹta yìí mọ́, àgbékà kọ̀ọ̀kan ga ní igbọnwọ marun-un, wọ́n sì fi pákó igi kedari so wọ́n pọ̀ mọ́ ara ilé ìsìn náà. OLUWA wí fún Solomoni ọba pé, “Ní ti ilé ìsìn tí ò ń kọ́ yìí, bí o bá pa gbogbo òfin mi mọ́, tí o sì tẹ̀lé ìlànà mi, n óo ṣe gbogbo ohun tí mo ṣèlérí fún Dafidi, baba rẹ, fún ọ. N óo máa gbé ààrin àwọn ọmọ Israẹli, n kò sì ní kọ eniyan mi sílẹ̀ laelae.” Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ṣe parí kíkọ́ ilé ìsìn náà. Pákó igi kedari ni ó fi bo ara ògiri ilé náà ninu, láti òkè dé ilẹ̀. Pákó igi sipirẹsi ni wọ́n sì fi tẹ́ gbogbo ilẹ̀ rẹ̀. Wọ́n kọ́ yàrá kan tí wọn ń pè ní Ibi-Mímọ́-Jùlọ, sí ọwọ́ ẹ̀yìn ilé ìsìn náà. Gígùn rẹ̀ jẹ́ ogún igbọnwọ, pákó kedari ni wọn fi gé e láti òkè dé ilẹ̀. Gbọ̀ngàn tí ó wà níwájú Ibi-Mímọ́-Jùlọ yìí gùn ní ogoji igbọnwọ. Wọ́n gbẹ́ àwòrán agbè ati òdòdó, wọ́n fi ṣe ọ̀ṣọ́ sára igi kedari tí wọ́n fi bo ògiri gbọ̀ngàn náà, òkúta tí wọ́n fi mọ ògiri ilé náà kò sì hàn síta rárá. Wọ́n kọ́ ibi mímọ́ kan sí ọwọ́ ẹ̀yìn ilé ìsìn náà, inú ibi mímọ́ yìí ni wọ́n gbé Àpótí Ẹ̀rí OLUWA sí. Gígùn ibi mímọ́ ti inú yìí jẹ́ ogún igbọnwọ, ó fẹ̀ ní ogún igbọnwọ, gíga rẹ̀ náà sì jẹ́ ogún igbọnwọ. Ojúlówó wúrà ni wọ́n fi bo gbogbo ibi mímọ́ náà; wọ́n sì fi pákó igi kedari ṣe pẹpẹ kan sibẹ. Ojúlówó wúrà ni Solomoni fi bo gbogbo inú ilé ìsìn náà, wọ́n sì so ẹ̀wọ̀n kan, ó fi dábùú ẹnu ọ̀nà ibi mímọ́ ti inú, ó sì yọ́ wúrà bò ó. Gbogbo inú ilé ìsìn náà patapata ni wọ́n fi wúrà bò, ati pẹpẹ tí ó wà ninu Ibi-Mímọ́-Jùlọ. Wọ́n fi igi olifi gbẹ́ ẹ̀dá abìyẹ́ meji tí wọn ń pè ní Kerubu, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ga ní igbọnwọ mẹ́wàá, wọ́n kó wọn sinu Ibi-Mímọ́-Jùlọ náà. Ìyẹ́ kọ̀ọ̀kan àwọn Kerubu mejeeji gùn ní igbọnwọ marun-un, tí ó fi jẹ́ pé láti ṣóńṣó ìyẹ́ kinni Kerubu kọ̀ọ̀kan dé ṣóńṣo ìyẹ́ rẹ̀ keji jẹ́ igbọnwọ mẹ́wàá. Gígùn ìyẹ́ mejeeji Kerubu keji náà jẹ́ igbọnwọ mẹ́wàá. Bákan náà ni àwọn Kerubu mejeeji yìí rí, bákan náà sì ni títóbi wọn. Ekinni keji wọn ga ní igbọnwọ mẹ́wàá. Ó gbé wọn kalẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn ninu Ibi-Mímọ́-Jùlọ. Àwọn mejeeji na ìyẹ́ wọn tí ó fi jẹ́ pé ọ̀kan ninu àwọn ìyẹ́ Kerubu kinni kan ògiri yàrá ní ẹ̀gbẹ́ kan, ọ̀kan ninu àwọn ìyẹ́ Kerubu keji sì kan ògiri yàrá ní ẹ̀gbẹ́ keji. Ìyẹ́ keji Kerubu kinni ati ìyẹ́ kinni Kerubu keji sì kan ara wọn ní ààrin yàrá náà. Wúrà ni wọ́n yọ́ bo àwọn Kerubu náà. Wọ́n gbẹ́ àwòrán igi ọ̀pẹ, ati ti òdòdó, ati ti Kerubu yípo ara ògiri yàrá tí ó wà ninu ati èyí tí ó wà lóde; wọ́n sì yọ́ wúrà bo ilẹ̀ àwọn yàrá náà. Wọ́n ri ìlẹ̀kùn meji, alápapọ̀, tí wọ́n fi igi olifi ṣe, mọ́ ẹnu ọ̀nà Ibi-Mímọ́-Jùlọ. Àtẹ́rígbà ìlẹ̀kùn náà rí ṣóńṣó ní ààrin, wọ́n gbẹ́ igi ọ̀pẹ, ati òdòdó, ati kerubu sí ara àwọn ìlẹ̀kùn náà; wọ́n sì yọ́ wúrà bò wọ́n patapata: ati igi ọ̀pẹ, ati òdòdó, ati àwọn Kerubu náà. Wọ́n fi igi olifi ṣe férémù ìlẹ̀kùn onígun mẹrin, wọ́n rì í mọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọ gbọ̀ngàn ńlá. Wọn fi igi sipirẹsi ṣe ìlẹ̀kùn meji, ekinni keji ní awẹ́ meji, awẹ́ ekinni keji sì ṣe é pàdé mọ́ ara wọn. Wọ́n gbẹ́ igi ọ̀pẹ, ati òdòdó, ati àwọn kerubu sí ara àwọn ìlẹ̀kùn náà, wọ́n sì fi wúrà bo gbogbo wọn. Bí wọ́n ṣe mọ ògiri àgbàlá inú ilé ìsìn náà ni pé, bí wọ́n bá mọ ìlè òkúta mẹta wọn a mọ ìlè igi kedari kan. Ninu oṣù Sifi, ní ọdún kẹrin ìjọba Solomoni, ni wọ́n fi ìpìlẹ̀ ilé ìsìn náà sọlẹ̀. Ninu oṣù Bulu, ní ọdún kọkanla ìjọba Solomoni ni wọ́n kọ́ ilé ìsìn náà parí patapata, ó sì rí bí wọ́n ti ṣètò pé kó rí gẹ́lẹ́. Ọdún meje ni ó gba Solomoni láti parí rẹ̀. Ọdún mẹtala ni Solomoni fi parí kíkọ́ ilé ti ara rẹ̀. Ọ̀kan ninu àwọn ilé tí ó kọ́ sí ààfin náà ni Ilé Igbó Lẹbanoni. Ilé náà gùn ní ọgọrun-un (100) igbọnwọ, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ, ó sì ga ní ọgbọ̀n igbọnwọ. Orí òpó igi kedari, tí wọ́n na ọ̀pá àjà igi kedari lé, ni wọ́n kọ́ ọ lé. Wọ́n to àwọn òpó, tí wọ́n kọ́ ilé yìí lé lórí, ní ìlà mẹta. Òpó mẹẹdogun mẹẹdogun wà ní ìlà kọ̀ọ̀kan. Wọ́n wá na ìtì igi kedari lé àwọn òpó náà lórí. Ìlà mẹta mẹta ni wọ́n to fèrèsé sí, àwọn fèrèsé ilé náà kọjú sí ara wọn ní àgbékà mẹta. Onígun mẹrin ni wọ́n ṣe férémù tí wọ́n fi ṣe àwọn ẹnu ọ̀nà ati fèrèsé ilé náà, wọ́n to àwọn fèrèsé ní ìlà mẹta mẹta ninu ògiri, ni àgbékà àgbékà, lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji ilé náà; wọ́n dojú kọ ara wọn. Ó kọ́ gbọ̀ngàn kan tí ó sọ ní gbọ̀ngàn Olópòó. Gígùn rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ. Ó ní ìloro kan tí wọ́n kọ́ sórí òpó; wọ́n ta nǹkan bò ó lórí. Ó kọ́ gbọ̀ngàn ìtẹ́ kan, níbi tí yóo ti máa dájọ́; igi kedari ni wọ́n fi ṣe ara ògiri rẹ̀ láti òkè délẹ̀. Ó kọ́ ilé tí òun alára óo máa gbé sí àgbàlá tí ó wà lẹ́yìn gbọ̀ngàn bí ó ti kọ́ àwọn ilé yòókù; ó sì kọ́ irú gbọ̀ngàn yìí gan-an fún ọmọ ọba Farao tí ó gbé ní iyawo. Òkúta olówó ńlá, tí wọ́n fi ayùn gé tinú-tẹ̀yìn, ni wọ́n fi kọ́ gbogbo ilé ati àgbàlá rẹ̀, láti ìpìlẹ̀ títí dé òrùlé rẹ̀, ati láti àgbàlá ilé OLUWA títí dé àgbàlá ńlá náà. Òkúta ńláńlá, olówó ńláńlá, onígbọ̀nwọ́ mẹjọ ati onígbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ni wọ́n fi ṣe ìpìlẹ̀ ilé náà. Òkúta olówó ńlá tí a wọ̀n kí á tó gé e, ati igi kedari, ni wọ́n fi ṣe ògiri rẹ̀. Ìlè mẹta mẹta òkúta gbígbẹ́ tí a fi ìlé kan igi kedari là láàrin, ni wọ́n fi kọ́ àgbàlá ńlá náà yípo. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni àgbàlá ti inú ilé OLUWA ati yàrá àbáwọlé. Solomoni ọba ranṣẹ pé kí wọ́n lọ mú Huramu wá láti Tire, ará Tire ni baba rẹ̀, ṣugbọn opó ọmọ ẹ̀yà Nafutali kan ni ìyá rẹ̀. Baba rẹ̀ ti jáde láyé, ṣugbọn nígbà ayé rẹ̀, òun náà mọ iṣẹ́ àgbẹ̀dẹ bàbà dáradára. Huramu gbọ́n, ó lóye, ó sì mọ bí a tíí fi idẹ ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà. Ó tọ Solomoni lọ, ó sì bá a ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ̀. Ó fi bàbà ṣe òpó meji; gíga ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ igbọnwọ mejidinlogun, àyíká rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mejila, ó ní ihò ninu, nínípọn rẹ̀ sì jẹ́ ìka mẹrin. Bákan náà ni òpó keji. Ó sì rọ ọpọ́n bàbà meji, ó gbé wọn ka orí àwọn òpó náà. Gíga àwọn ọpọ́n náà jẹ́ igbọnwọ marun-un marun-un. Ó fi irin hun àwọ̀n meji fún àwọn ọpọ́n orí mejeeji tí wọ́n wà lórí àwọn òpó náà, àwọ̀n kọ̀ọ̀kan fún ọpọ́n orí òpó kọ̀ọ̀kan. Bákan náà ni ó ṣe èso pomegiranate ní ìlà meji, ó fi wọ́n yí iṣẹ́ ọnà àwọ̀n náà po, ó sì fi dárà sí ọpọ́n tí ó wà lórí òpó. Bákan náà ni ó ṣe sí ọpọ́n orí òpó keji. Wọ́n ṣe ọpọ́n orí òpó inú yàrá àbáwọlé náà bí ìtànná lílì, ó ga ní igbọnwọ mẹrin. Ọpọ́n kọ̀ọ̀kan wà lórí òpó mejeeji, lórí ibi tí ó yọ jáde tí ó rí bìrìkìtì lára àwọn òpó, lẹ́gbẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ọnà náà. Igba èso pomegiranate ni wọ́n fi yí àwọn òpó náà ká ní ọ̀nà meji. Bẹ́ẹ̀ ló ṣe sí òpó keji pẹlu. Ó ri àwọn òpó mejeeji yìí sí àbáwọ Tẹmpili, wọ́n ri ọ̀kan sí ìhà gúsù, wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Jakini; wọ́n ri ekeji sí apá àríwá, wọ́n sì pè é ní Boasi. Iṣẹ́ ọnà ìtànná lílì ni wọ́n ṣe sára àwọn òpó náà. Bẹ́ẹ̀ ni iṣẹ́ ṣe parí lórí àwọn òpó náà. Ó ṣe agbada omi rìbìtì kan. Jíjìn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ marun-un ààbọ̀, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹ́wàá. Àyíká rẹ̀ sì jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ. Wọ́n fi idẹ ṣe ọpọlọpọ agbè, wọ́n tò wọ́n ní ìlà meji sí etí agbada omi náà. Láti ilẹ̀ ni wọ́n ti ṣe àwọn agbè yìí ní àṣepọ̀ mọ́ agbada omi náà. Wọ́n gbé agbada yìí ka orí akọ mààlúù mejila, tí wọ́n fi bàbà ṣe. Mẹta ninu àwọn mààlúù náà dojú kọ apá ìhà àríwá, àwọn mẹta dojú kọ apá ìwọ̀ oòrùn, àwọn mẹta dojú kọ apá gúsù, àwọn mẹta sì dojú kọ apá ìlà oòrùn. Agbada náà nípọn ní ìwọ̀n ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan. Etí rẹ̀ dàbí etí ife omi, ó tẹ̀ ní àtẹ̀sóde bí ìsàlẹ̀ òdòdó lílì. Agbada náà lè gbà tó ẹgbaa (2,000) galọọnu omi. Huramu tún fi bàbà ṣe ìtẹ́lẹ̀ mẹ́wàá, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gùn ní igbọnwọ mẹrin, wọ́n fẹ̀ ní igbọnwọ mẹrin, wọ́n sì ga ní igbọnwọ mẹta. Báyìí ni wọ́n ṣe mọ àwọn ìtẹ́lẹ̀ náà: wọ́n ní ìtẹ́dìí, àwọn ìtẹ́dìí yìí sì ní igun mẹrin mẹrin, lórí àwọn ìtẹ́dìí yìí ni ó ya àwòrán àwọn kinniun, mààlúù ati ti kerubu sí. Wọ́n ṣe àwọn ọnà róbótó róbótó kan báyìí sí òkè àwọn kinniun ati akọ mààlúù náà ati sí ìsàlẹ̀ wọn. Olukuluku ìtẹ́lẹ̀ yìí ni ó ní àgbá kẹ̀kẹ́ idẹ mẹrin, igun mẹrẹẹrin rẹ̀ sì ní ìtẹ́lẹ̀, lábẹ́ agbada náà ni àwọn ìtẹ́lẹ̀ tí a rọ wà. A ṣe ọ̀ṣọ́ sí gbogbo igun ìtẹ́lẹ̀ náà, òkè agbada náà dàbí adé tí a yọ sókè ní igbọnwọ kan, wọ́n sì ṣe iṣẹ́ ọnà aláràbarà yí etí rẹ̀ po. Àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ mẹrẹẹrin wà lábẹ́ àwọn ìtẹ́dìí yìí, àṣepọ̀ mọ́ ìtẹ́lẹ̀ ni wọ́n ṣe àwọn ọ̀pá inú àgbá kẹ̀kẹ́ náà. Gíga àgbá kẹ̀kẹ́ kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀. Ó ṣe àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ yìí bíi ti kẹ̀kẹ́ ogun, dídà ni wọ́n dà á ati irin tí àgbá náà fi ń yí, ati riimu wọn, ati sipoku ati họọbu wọn. Ìtẹ́lẹ̀ mẹrin mẹrin ló wà ní orígun mẹrẹẹrin àwọn ìtẹ́dìí náà, ẹyọ kan náà ni wọ́n ṣe àwọn ìtẹ́lẹ̀ pẹlu ìtẹ́dìí yìí. A mọ ìgbátí yíká òkè àwọn ìtẹ́lẹ̀ náà, tí ó ga sókè ní ààbọ̀ igbọnwọ, ìgbátí yìí wà ní téńté orí àwọn ìtẹ́lẹ̀ náà. Àṣepọ̀ ni wọ́n ṣe òun ati ìtẹ́dìí rẹ̀. Ó ya àwòrán àwọn kerubu, ati kinniun ati ti igi ọ̀pẹ sí orí àwọn ìtẹ́lẹ̀ ati ìtẹ́dìí yìí, bí ààyè ti wà fún olukuluku sí; ó sì ṣe òdòdó sí i yípo. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe ṣe ìtẹ́lẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá, bákan náà ni ó da gbogbo wọn, bákan náà ni wọ́n tó, bákan náà ni wọn sì rí. Ó ṣe abọ́ bàbà ńlá mẹ́wàá, ọ̀kọ̀ọ̀kan gba igba galọọnu, ó sì jẹ́ igbọnwọ mẹrin. Abọ́ kọ̀ọ̀kan sì wà lórí ìtẹ̀lẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá. Ó to ìtẹ́lẹ̀ marun-un marun-un sí apá ìhà gúsù ati apá ìhà àríwá ilé náà, ó sì gbé agbada omi sí igun tí ó wà ní agbedemeji ìhà gúsù ati ìhà ìlà oòrùn ilé náà. Huramu mọ ọpọlọpọ ìkòkò, ó fi irin rọ ọkọ́ pupọ, ó sì ṣe àwọn àwo kòtò. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe parí iṣẹ́ tí ó bá Solomoni ọba ṣe ninu ilé OLUWA. Àwọn iṣẹ́ náà nìwọ̀nyí: Òpó meji, ati àwọn ọpọ́n rìbìtì rìbìtì meji tí ó wà lórí àwọn òpó náà, ati iṣẹ́ ọnà tí ó ṣe sí ara àwo meji tí ó wà lórí ọpọ́n. Àwọn irinwo pomegiranate tí wọ́n tò sí ìlà meji yí ọpọ́n bìrìkìtì bìrìkìtì orí àwọn òpó náà ká, ní ọgọọgọrun-un. Ó ṣe agbada omi mẹ́wàá ati ìtẹ́dìí kọ̀ọ̀kan fún wọn. Ó ṣe agbada omi ńlá kan ati àwọn ère mààlúù mejila tí wọ́n wà ní abẹ́ rẹ̀. Bàbà dídán ni Huramu fi ṣe àwọn ìkòkò ati ọkọ́ ati àwokòtò ati gbogbo ohun èlò inú ilé OLUWA tí ó ṣe fún Solomoni ọba. Ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jọdani tí ó jẹ́ ilẹ̀ amọ̀, láàrin Sukotu ati Saretani, ni ọba ti ṣe wọ́n. Solomoni kò wọn àwọn ohun èlò tí ó ṣe, nítorí wọ́n pọ̀ yanturu. Nítorí náà kò mọ ìwọ̀n bàbà tí ó lò. Solomoni ṣe gbogbo àwọn ohun èlò wọnyi sinu ilé OLUWA: pẹpẹ wúrà, tabili wúrà fún burẹdi ìfihàn; àwọn ọ̀pá fìtílà tí wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe: marun-un ní ìhà àríwá, ati marun-un ní ìhà gúsù níwájú Ibi-Mímọ́-Jùlọ; àwọn òdòdó, àwọn fìtílà, ati àwọn ẹ̀mú wúrà, àwọn ife ati ọ̀pá tí wọ́n fi ń pa iná ẹnu fìtílà; àwokòtò ati àwo turari, àwo ìfọnná tí wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe, wọ́n fi wúrà ṣe àwọn ihò àgbékọ́ ìlẹ̀kùn Ibi-Mímọ́-Jùlọ ati ti ìlẹ̀kùn gbọ̀ngàn Tẹmpili náà. Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ọba ṣe parí gbogbo iṣẹ́ kíkọ́ ilé OLUWA, ó kó gbogbo fadaka, wúrà, ati àwọn ohun èlò inú ilé ìsìn, tí Dafidi, baba rẹ̀, ti yà sí mímọ́ wá, ó sì fi wọ́n pamọ́ sinu àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ninu ilé OLUWA. Lẹ́yìn náà, Solomoni ọba ranṣẹ sí àwọn àgbààgbà Israẹli: àwọn olórí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, ati gbogbo àwọn olórí ìdílé kọ̀ọ̀kan, ó pè wọ́n jọ sí Jerusalẹmu láti gbé Àpótí Ẹ̀rí OLUWA láti Sioni, ìlú Dafidi, wá sinu ilé OLÚWA. Gbogbo wọ́n bá péjọ siwaju rẹ̀ ní àkókò àjọ̀dún, ní oṣù Etanimu, tíí ṣe oṣù keje ọdún. Lẹ́yìn tí gbogbo àwọn àgbààgbà ti péjọ, àwọn alufaa gbé Àpótí Ẹ̀rí náà. Àwọn ọmọ Lefi ati àwọn alufaa gbé Àpótí OLUWA wá, ati Àgọ́ OLUWA, ati àwọn ohun èlò mímọ́ tí ó wà ninu rẹ̀. Solomoni ọba ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli péjọ níwájú Àpótí Ẹ̀rí OLUWA, wọ́n sì fi ọpọlọpọ aguntan ati mààlúù tí ẹnikẹ́ni kò lè kà rúbọ. Lẹ́yìn náà, àwọn alufaa gbé Àpótí Ẹ̀rí OLUWA wá sí ààyè rẹ̀ ninu ibi mímọ́ ti inú, ní Ibi-Mímọ́-Jùlọ, lábẹ́ ìyẹ́ àwọn kerubu. Nítorí àwọn kerubu yìí na ìyẹ́ wọn bo ibi tí wọ́n gbé Àpótí Ẹ̀rí náà sí, wọ́n sì dàbí ìbòrí fún Àpótí Ẹ̀rí ati àwọn ọ̀pá rẹ̀. Àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi ń gbé Àpótí Ẹ̀rí náà gùn tóbẹ́ẹ̀ tí ẹni tí ó bá dúró ninu Ibi-Mímọ́ fi lè rí orí wọn níwájú Ibi-Mímọ́ ti inú. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò lè rí wọn láti ìta. Àwọn ọ̀pá náà wà níbẹ̀ títí di òní yìí. Kò sí ohunkohun ninu Àpótí Ẹ̀rí náà, àfi tabili òkúta meji tí Mose kó sinu rẹ̀ ní òkè Sinai, níbi tí OLUWA ti bá àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu, nígbà tí wọn ń ti Ijipti bọ̀. Bí àwọn alufaa ti jáde láti inú Ibi-Mímọ́ náà, ìkùukùu kún inú rẹ̀, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn alufaa kò lè dúró láti ṣe iṣẹ́ ìsìn, nítorí ògo OLUWA kún inú ilé OLUWA. Solomoni bá gbadura, ó ní, “OLUWA, ìwọ ni o fi oòrùn sí ojú ọ̀run, ṣugbọn sibẹsibẹ o yàn láti gbé inú ìkùukùu ati òkùnkùn biribiri. Nisinsinyii mo ti kọ́ ilé kan tí ó lọ́lá fún ọ, níbi tí o óo máa gbé títí lae.” Solomoni ọba yipada, ó kọjú sí àwọn eniyan níbi tí wọ́n dúró sí, ó sì súre fún wọn. Ó ní, “Ìyìn ni fún OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí ó mú ìlérí tí ó ṣe fún Dafidi, baba mi, ṣẹ, tí ó ní, ‘Láti ìgbà tí mo ti kó àwọn eniyan mi jáde láti ilẹ̀ Ijipti, n kò yan ìlú kan ninu gbogbo ilẹ̀ Israẹli pé kí àwọn ọmọ Israẹli kọ́ ilé ìsìn sibẹ, níbi tí wọn óo ti máa sìn mí, ṣugbọn, mo yan Dafidi láti jọba lórí Israẹli, eniyan mi.’ ” Solomoni tún fi kún un pé, “Ó jẹ́ èrò ọkàn baba mi láti kọ́ ilé fún OLUWA Ọlọrun Israẹli. Ṣugbọn OLUWA sọ fún un pé nítòótọ́, ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ ni láti kọ́ ilé fún mi, ó sì dára bẹ́ẹ̀, ṣugbọn kì í ṣe òun ni yóo kọ́ ilé ìsìn náà, ọmọ bíbí rẹ̀ ni yóo kọ́ ọ. “Nisinsinyii OLUWA ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ: mo ti gorí oyè lẹ́yìn Dafidi, baba mi, mo ti jọba ní ilẹ̀ Israẹli bí OLUWA ti ṣèlérí; mo sì ti kọ́ ilé fún OLUWA Ọlọrun Israẹli. Mo ti ṣètò ibìkan ninu ilé náà fún Àpótí Ẹ̀rí OLUWA, tí tabili òkúta tí wọ́n kọ majẹmu sí wà ninu rẹ̀, majẹmu tí OLUWA bá àwọn baba ńlá wa dá nígbà tí ó ń kó wọn jáde láti ilẹ̀ Ijipti.” Solomoni dúró níwájú pẹpẹ níwájú àwùjọ àwọn ọmọ Israẹli, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ mejeeji sókè. Ó bẹ̀rẹ̀ sí gbadura, ó ní, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, kò sí Ọlọrun kan tí ó dàbí rẹ̀ lókè ọ̀run tabi ní ayé yìí, tíí máa pa majẹmu rẹ̀ mọ́, tíí sì máa fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn iranṣẹ rẹ̀, tí ń fi tọkàntọkàn gbọ́ràn sí i lẹ́nu. O ti mú ìlérí tí o ṣe fún iranṣẹ rẹ, Dafidi, baba mi, ṣẹ. O ṣe ìlérí fún un nítòótọ́, o sì mú un ṣẹ lónìí. Ǹjẹ́ nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun Israẹli, mo bẹ̀ ọ́, mú àwọn ìlérí tí o ṣe fún iranṣẹ rẹ, Dafidi, baba mi ṣẹ, pé, arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo máa jọba ní Israẹli títí lae, bí wọ́n bá ṣọ́ra ní ọ̀nà wọn, tí wọ́n sì bá mi rìn bí ìwọ ti bá mi rìn. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun Israẹli, mú ìlérí tí o ṣe fún iranṣẹ rẹ, Dafidi, baba mi ṣẹ. “Ṣugbọn, ǹjẹ́ ìwọ Ọlọrun lè gbé inú ayé yìí? Nítorí pé bí gbogbo ọ̀run ti tóbi tó, kò gbà ọ́; kí á má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti ilé ìsìn tí mo kọ́ fún ọ? OLUWA Ọlọrun mi, fi etí sí adura èmi iranṣẹ rẹ, kí o sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ tí mò ń bẹ̀ níwájú rẹ lónìí. Kí ojú rẹ lè máa wà lára ilé ìsìn yìí tọ̀sán-tòru, níbi tí o sọ pé o óo yà sọ́tọ̀ fún orúkọ rẹ. Kí o lè gbọ́ adura tí iranṣẹ rẹ ń gbà sí ibí yìí. Máa gbọ́ ẹ̀bẹ̀ iranṣẹ rẹ ati adura àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, nígbà tí wọ́n bá kọjú sí ilé yìí, tí wọ́n sì gbadura, máa gbọ́ tiwa láti ibùgbé rẹ lọ́run, kí o sì máa dáríjì wá. “Bí ẹnìkan bá ṣẹ ọmọnikeji rẹ̀ tí wọ́n sì ní kí ó wá búra, tí ó bá wá tí ó sì búra níwájú pẹpẹ rẹ ninu ilé ìsìn yìí, OLUWA, gbọ́ lọ́run lọ́hùn-ún, kí o sì ṣe ìdájọ́ àwọn iranṣẹ rẹ. Jẹ ẹni tí ó bá jẹ̀bi ní ìyà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; dá ẹni tí ó bá jàre láre, kí o sì san ẹ̀san òdodo rẹ̀ fún un. “Nígbà tí àwọn ọ̀tá bá ṣẹgun àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, nítorí pé wọ́n dẹ́ṣẹ̀ sí ọ́, lẹ́yìn náà, tí wọ́n bá tún yipada sí ọ, tí wọ́n jẹ́wọ́ orúkọ rẹ ninu ilé yìí, tí wọ́n gbadura sí ọ, tí wọ́n bẹ̀bẹ̀, gbọ́ adura wọn lọ́run lọ́hùn-ún, dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, kí o sì mú wọn pada wá sórí ilẹ̀ tí o fún àwọn baba ńlá wọn. “Nígbà tí o kò bá jẹ́ kí òjò rọ̀, nítorí pé wọ́n ṣẹ̀ ọ́, tí wọ́n bá ronupiwada tí wọ́n sì kọjú sí ilé ìsìn yìí, tí wọ́n gbadura sí ọ, nígbà tí o bá jẹ wọ́n níyà, gbọ́ adura wọn lọ́run lọ́hùn-ún, dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji Israẹli, iranṣẹ rẹ, àní, àwọn eniyan rẹ, kí o sì kọ́ wọn ní ọ̀nà rere tí wọn yóo máa tọ̀; lẹ́yìn náà, rọ òjò sórí ilẹ̀ rẹ tí o fi fún àwọn eniyan rẹ bí ohun ìní. “Nígbà tí ìyàn bá mú ní ilẹ̀ yìí, tabi tí àjàkálẹ̀ àrùn wà, tabi ìrẹ̀dànù èso, tabi tí ọ̀wọ́ eṣú, tabi tí àwọn kòkòrò bá jẹ ohun ọ̀gbìn oko run, tabi tí àwọn ọ̀tá bá dó ti èyíkéyìí ninu ìlú àwọn eniyan rẹ, tabi tí àìsàn, tabi àrùnkárùn kan bá wà láàrin wọn, gbọ́ adura tí wọ́n bá gbà, ati ẹ̀bẹ̀ tí ẹnikẹ́ni tabi gbogbo Israẹli, àwọn eniyan rẹ, bá bẹ̀, nítorí ìpọ́njú ọkàn olukuluku wọn. Tí wọ́n bá gbé ọwọ́ wọn sókè, tí wọ́n sì kọjú sí ilé ìsìn yìí, gbọ́ adura wọn láti ibùgbé rẹ lọ́run, dáríjì wọ́n, dá wọn lóhùn, kí o sì san ẹ̀san fún olukuluku gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀, (nítorí ìwọ nìkan ni o mọ èrò ọkàn ọmọ eniyan); kí wọ́n lè máa bẹ̀rù rẹ ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n óo gbé lórí ilẹ̀ tí o fi fún àwọn baba ńlá wọn. “Bákan náà, nígbà tí àlejò kan, tí kì í ṣe ọmọ Israẹli, bá wá láti ilẹ̀ òkèèrè nítorí orúkọ rẹ, (nítorí wọn óo gbọ́ òkìkí rẹ, ati iṣẹ́ ìyanu tí o ti ṣe fún àwọn eniyan rẹ); tí ó bá wá sìn ọ́, tí ó bá kọjú sí ilé yìí, tí ó gbadura, gbọ́ adura rẹ̀ láti ibùgbé rẹ lọ́run, kí o sì ṣe gbogbo ohun tí ó bá bèèrè fún un, kí gbogbo aráyé lè mọ orúkọ rẹ, kí wọ́n sì lè bẹ̀rù rẹ bí àwọn ọmọ Israẹli, àwọn eniyan rẹ tí ń ṣe, wọn yóo sì mọ̀ pé ilé ìsìn rẹ ni ilé tí mo kọ́ yìí. “Nígbà tí àwọn eniyan rẹ bá lọ dojú kọ àwọn ọ̀tá wọn lójú ogun, níbikíbi tí o bá rán wọn lọ, tí wọ́n bá kọjú sí ìlú tí o yàn yìí, ati ilé ìsìn tí mo kọ́ fún ọ, tí wọ́n sì gbadura, gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ wọn láti ọ̀run wá, kí o sì tì wọ́n lẹ́yìn. “Nígbà tí àwọn eniyan rẹ bá ṣẹ̀ ọ́, (nítorí pé kò sí ẹni tí kì í dẹ́ṣẹ̀), tí o bá bínú sí wọn, tí o sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá ṣẹgun wọn, tí wọ́n sì kó wọn lẹ́rú lọ sí ilẹ̀ mìíràn, kì báà jẹ́ ibi tí ó jìnnà tabi tòsí, bí wọ́n bá ronupiwada ní ilẹ̀ tí wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ, tí wọ́n sì rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ọ, tí wọ́n bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá, ati ìwà burúkú tí wọ́n hù, tí wọ́n bá ronupiwada tọkàntọkàn ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn tí ó kó wọn lẹ́rú, tí wọ́n bá kọjú sí ilẹ̀ tí o fi fún àwọn baba ńlá wọn, ati ìlú tí o yàn yìí, ati ilé ìsìn tí mo kọ́ ní orúkọ rẹ, tí wọ́n bá gbadura sí ọ; gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ wọn láti ibùgbé rẹ lọ́run, kí o sì tì wọ́n lẹ́yìn. Dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, ati gbogbo àìdára tí wọ́n ṣe, kí o sì jẹ́ kí àwọn tí wọ́n kó wọn lẹ́rú ṣàánú wọn. Eniyan rẹ sá ni wọ́n, ìwọ ni o sì ni wọ́n, ìwọ ni o kó wọn jáde láti ilẹ̀ Ijipti, ilẹ̀ tí ó gbóná janjan bí iná ìléru. “OLUWA Ọlọrun, fi ojurere wo àwa iranṣẹ rẹ, àní àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, kí o sì gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ wọn nígbàkúùgbà tí wọ́n bá ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́. OLUWA Ọlọrun, ìwọ ni o yà wọ́n sọ́tọ̀ láàrin gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ayé, pé kí wọ́n jẹ́ ìní rẹ, gẹ́gẹ́ bí o ti sọ fún wọn láti ẹnu Mose, iranṣẹ rẹ, nígbà tí ó kó àwọn baba ńlá wa jáde ní ilẹ̀ Ijipti.” Nígbà ti Solomoni parí adura ati ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ sí OLUWA, ó dìde kúrò níwájú pẹpẹ níbi tí ó kúnlẹ̀ sí, tí ó sì gbé ọwọ́ sókè. Ó dìde dúró, ó sì súre fún gbogbo ìjọ ọmọ Israẹli, ó gbadura sókè pé, “Ìyìn ni fún OLUWA, tí ó fún àwọn eniyan rẹ̀ ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀. Ó ti mú gbogbo ìlérí rere rẹ̀ tí ó ṣe láti ẹnu Mose, iranṣẹ rẹ̀, ṣẹ. Kí OLUWA Ọlọrun wa kí ó wà pẹlu wa, bí ó ti wà pẹlu àwọn baba ńlá wa; kí ó má fi wá sílẹ̀, kí ó má sì kọ̀ wá sílẹ̀, kí ó ṣe wá ní ẹni tí yóo gbọ́ràn sí òun lẹ́nu, kí á lè máa tọ ọ̀nà rẹ̀, kí á lè máa pa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀ tí ó fi fún àwọn baba ńlá wa mọ́. Kí OLUWA Ọlọrun wa ranti adura mi yìí ati gbogbo ẹ̀bẹ̀ tí mo bẹ̀ níwájú rẹ̀ yìí tọ̀sán-tòru, kí ó máa ti èmi iranṣẹ rẹ̀ lẹ́yìn nígbà gbogbo, ati àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ̀ pẹlu; máa tì wá lẹ́yìn bí ó bá ti tọ́ lojoojumọ, kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ayé lè mọ̀ pé OLUWA ni Ọlọrun, ati pé kò sí ẹlòmíràn mọ́. Ẹ fi tọkàntọkàn jẹ́ olóòótọ́ sí OLUWA Ọlọrun wa, kí ẹ tẹ̀lé ìlànà rẹ̀, kí ẹ sì máa pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ bí ẹ ti ń ṣe lónìí.” Lẹ́yìn náà, Solomoni ọba ati gbogbo àwọn eniyan rú ẹbọ sí OLUWA. Solomoni fi ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaa (22,000) mààlúù, ati ọ̀kẹ́ mẹfa (120,000) aguntan rú ẹbọ alaafia sí OLUWA. Bẹ́ẹ̀ ni òun ati àwọn ọmọ Israẹli ṣe ya ilé OLUWA náà sí mímọ́. Ní ọjọ́ kan náà, ọba ya ààrin gbùngbùn àgbàlá tí ó wà níwájú ilé ìsìn sí mímọ́. Níbẹ̀ ni ó ti rú ẹbọ sísun, ati ẹbọ ohun jíjẹ, ati ti ọ̀rá ẹran tí ó fi rú ẹbọ alaafia; nítorí pé pẹpẹ bàbà tí ó wà níwájú OLUWA kéré jù fún àpapọ̀ gbogbo àwọn ẹbọ wọnyi. Solomoni ati àwọn ọmọ Israẹli ṣe Àjọ̀dún Àgọ́ Àjọ níbẹ̀. Ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan láti Ẹnu Ọ̀nà Hamati títí dé odò kékeré Ijipti ni wọ́n péjọ níwájú OLUWA fún ọjọ́ meje. Ní ọjọ́ kẹjọ Solomoni tú àwọn eniyan náà ká lọ sí ilé wọn. Gbogbo wọn ni wọ́n súre fún ọba, wọ́n sì pada sílé pẹlu inú dídùn; nítorí gbogbo oore tí OLUWA ti ṣe fún Dafidi, iranṣẹ rẹ̀, ati fún àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ̀. Lẹ́yìn tí Solomoni ọba ti kọ́ ilé OLUWA ati ààfin rẹ̀ tán, ati gbogbo ilé tí ó fẹ́ kọ́. OLUWA tún fi ara hàn án lẹẹkeji, bí ó ti fara hàn án ní Gibeoni, ó wí fún un pé, “Mo ti gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ rẹ, mo sì ti ya ilé tí o kọ́ yìí sí mímọ́. Ibẹ̀ ni wọn óo ti máa sìn mí títí lae. N óo máa mójú tó o, n óo sì máa dáàbò bò ó nígbà gbogbo. Bí o bá sìn mí tọkàntọkàn pẹlu òtítọ́ inú, gẹ́gẹ́ bí Dafidi, baba rẹ, ti ṣe, bí o bá ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ, tí o sì pa òfin ati ìlànà mi mọ́, n óo fìdí ìjọba rẹ múlẹ̀ ní Israẹli, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣèlérí fún Dafidi, baba rẹ, pé arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo máa jọba lórí àwọn ọmọ Israẹli títí lae. Ṣugbọn bí ìwọ tabi arọmọdọmọ rẹ bá yapa kúrò lẹ́yìn mi, tí ẹ bá ṣe àìgbọràn sí àwọn òfin ati ìlànà tí mo fi lélẹ̀ fún yín, tí ẹ bẹ̀rẹ̀ sí bọ oriṣa, n óo mú àwọn ọmọ Israẹli kúrò lórí ilẹ̀ tí mo fún wọn, n óo sì kọ ilé ìsìn tí mo ti yà sí mímọ́ fún orúkọ mi sílẹ̀. Gbogbo ọmọ Israẹli yóo di ẹni àmúpòwe ati ẹlẹ́yà láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù. Ilé yìí yóo di òkìtì àlàpà, yóo sì di ohun àwòyanu ati ẹ̀gàn fún gbogbo ẹni tí ó bá ń rékọjá lọ. Wọn óo máa bi ara wọn léèrè pé, ‘Kí ló dé tí OLUWA fi ṣe báyìí sí ilẹ̀ yìí ati ilé yìí?’ Wọn óo sì dáhùn pé, ‘Ìdí tí OLUWA fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé, àwọn eniyan náà kọ OLUWA Ọlọrun wọn, tí ó kó àwọn baba ńlá wọn jáde láti ilẹ̀ Ijipti sílẹ̀, wọ́n sì lọ ń forí balẹ̀ fún àwọn oriṣa, wọ́n ń sìn wọ́n; nítorí náà ni OLUWA fi jẹ́ kí ibi ó bá wọn.’ ” Lẹ́yìn ogún ọdún tí Solomoni fi kọ́ ilé OLUWA ati ààfin rẹ̀, tí Hiramu, ọba Tire sì ti fún un ní ìwọ̀n igi kedari, igi sipirẹsi ati wúrà tí ó fẹ́, fún iṣẹ́ náà, Solomoni fún Hiramu ní ogún ìlú ní agbègbè Galili. Ṣugbọn nígbà tí Hiramu ọba wá láti Tire tí ó rí àwọn ìlú tí Solomoni fún un, wọn kò tẹ́ ẹ lọ́rùn rárá. Ó bi Solomoni pé, “Arakunrin mi, irú àwọn ìlú wo ni o fún mi yìí?” Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe ilẹ̀ náà ní Kabulu títí di òní olónìí. Ọgọfa (120) ìwọ̀n talẹnti wúrà ni Hiramu ti fi ranṣẹ sí Solomoni ọba. Pẹlu ipá ni Solomoni ọba fi kó àwọn eniyan ṣiṣẹ́, tí ó fi kọ́ ilé OLUWA ati ààfin rẹ̀, ó sì kọ́ Milo, ati odi Jerusalẹmu, ati ìlú Hasori, ìlú Megido ati ìlú Geseri. (Farao, ọba Ijipti ti gbógun ti ìlú Geseri ó sì dáná sun ún, ó pa gbogbo àwọn ará Kenaani tí wọn ń gbé inú rẹ̀. Ó fi ìlú náà ṣe ẹ̀bùn igbeyawo fún ọmọ rẹ̀ obinrin, nígbà tí ó fẹ́ Solomoni ọba. Nítorí náà ni Solomoni ṣe tún ìlú náà kọ́.) Pẹlu apá ìsàlẹ̀ Beti Horoni, ati ìlú Baalati, ati Tamari tí ó wà ní aṣálẹ̀ Juda, ati àwọn ìlú tí ó ń kó àwọn ohun èlò rẹ̀ pamọ́ sí, ati àwọn ìlú tí ó ń kó kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ sí, ati àwọn ìlú tí àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ ń gbé, ati gbogbo ilé yòókù tí ó wu Solomoni láti kọ́ ní Jerusalẹmu, ní Lẹbanoni, ati ní àwọn ibòmíràn ninu ìjọba rẹ̀. Gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n ṣẹ́kù lára àwọn ará Amori, ati àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Perisi, ati àwọn ará Hifi ati àwọn ará Jebusi, àwọn tí kì í ṣe ara àwọn ọmọ Israẹli– arọmọdọmọ wọn tí wọ́n ṣẹ́kù, tí àwọn ọmọ Israẹli kò lè parun, ni Solomoni kó lẹ́rú pẹlu ipá, wọ́n sì wà bẹ́ẹ̀ títí di òní yìí. Ṣugbọn Solomoni kò fi àwọn ọmọ Israẹli ṣe ẹrú. Àwọn ni ó ń lò gẹ́gẹ́ bí ọmọ ogun, ati olórí àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀; àwọn ni balogun rẹ̀, ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀; àwọn ni ọ̀gá àwọn tí ń darí kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀. Ẹgbẹta ó dín aadọta (550) ni àwọn lọ́gàálọ́gàá tí Solomoni fi ṣe alákòóso àwọn tí ó ń kó ṣiṣẹ́ tipátipá, níbi oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ilé kíkọ́ rẹ̀. Nígbà tí ó yá, ọmọ ọba Farao, iyawo Solomoni kó kúrò ní ìlú Dafidi, ó lọ sí ilé tí Solomoni kọ́ fún un. Lẹ́yìn náà ni Solomoni kọ́ ìlú Milo. Ẹẹmẹta lọ́dún ni Solomoni máa ń rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia lórí pẹpẹ tí ó kọ́ fún OLUWA, a sì máa sun turari níwájú OLUWA. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe parí kíkọ́ ilé náà. Solomoni kan ọpọlọpọ ọkọ̀ ojú omi ní Esiongeberi lẹ́bàá Eloti, ní etí Òkun Pupa ní ilẹ̀ Edomu. Hiramu ọba fi àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n mọ̀ nípa ọkọ̀ ojú omi, lé àwọn ọkọ̀ náà, ó kó wọn rán àwọn iranṣẹ Solomoni sí i. Wọ́n tu ọkọ̀ lọ sí ilẹ̀ Ofiri, wọ́n sì kó wúrà tí ó tó okoolenirinwo (420) ìwọ̀n talẹnti bọ̀ wá fún Solomoni ọba. Nígbà tí ọbabinrin Ṣeba gbọ́ òkìkí ọgbọ́n Solomoni, ó wá sí Jerusalẹmu láti fi àwọn ìbéèrè tí ó takókó dán an wò. Ó kó ọpọlọpọ iranṣẹ lẹ́yìn, ó sì di turari olóòórùn dídùn, pẹlu òkúta olówó iyebíye ati ọpọlọpọ wúrà ru ọpọlọpọ ràkúnmí; ó wá sí Jerusalẹmu. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Solomoni, ó sọ gbogbo ohun tí ó wà lọ́kàn rẹ̀ patapata fún un. Solomoni dáhùn gbogbo àwọn ìbéèrè rẹ̀, kò sì sí ohunkohun tí ó le fún Solomoni láti ṣàlàyé. Nígbà tí ọbabinrin Ṣeba rí i bí Solomoni ti gbọ́n tó, ati irú ààfin tí ó kọ́, irú oúnjẹ tí ó wà lórí tabili rẹ̀, ìjókòó àwọn ìjòyè rẹ̀, ìṣesí àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati ìwọṣọ wọn, àwọn tí wọ́n ń gbé ọtí rẹ̀ ati ẹbọ sísun tí ó ń rú ninu ilé OLUWA, ẹnu yà á lọpọlọpọ. Ó sọ fún Solomoni ọba pé, “Òtítọ́ ni ìròyìn tí mo gbọ́ ní ìlú mi nípa ìjọba rẹ ati ọgbọ́n rẹ. Ṣugbọn n kò gbàgbọ́ títí tí mo fi wá, tí mo sì fi ojú ara mi rí i. Àwọn tí wọ́n sọ fún mi kò tilẹ̀ sọ ìdajì ohun tí mo rí. Ọgbọ́n, ati ọrọ̀ rẹ pọ̀ rékọjá ohun tí mo gbọ́ lọ. Àwọn iyawo rẹ ṣe oríire; bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn iranṣẹ rẹ wọnyi tí wọn ń wà lọ́dọ̀ rẹ nígbà gbogbo, tí wọn ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n rẹ! Ìyìn ni fún OLUWA Ọlọrun rẹ, ẹni tí inú rẹ̀ dùn sí ọ, tí ó sì fi ọ́ jọba Israẹli. Nítorí ìfẹ́ ayérayé tí ó ní sí Israẹli ni ó ṣe fi ọ́ jọba lórí wọn, kí o lè máa ṣe ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ati ti òdodo.” Lẹ́yìn náà, ọbabinrin Ṣeba fún Solomoni ọba ní ọgọfa (120) ìwọ̀n talẹnti wúrà, ati ọpọlọpọ turari olóòórùn dídùn, ati àwọn òkúta olówó iyebíye. Turari tí ọbabinrin Ṣeba fún Solomoni pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé Solomoni kò rí irú rẹ̀ gbà ní ẹ̀bùn mọ́. Àwọn ọkọ̀ ojú omi Hiramu ọba, tí ó kó wúrà wá láti Ofiri kó ọpọlọpọ igi alimugi ati òkúta olówó iyebíye bọ̀ pẹlu. Solomoni ọba fi igi alimugi náà ṣe òpó ilé OLUWA ati ti ààfin rẹ̀. Ó tún lò ninu wọn, ó fi ṣe ohun èlò orin tí wọ́n ń pè ní hapu ati gòjé fún àwọn akọrin rẹ̀. Ẹnikẹ́ni kò rí irú igi alimugi bẹ́ẹ̀ mọ́ ní ilẹ̀ Israẹli títí di òní olónìí. Gbogbo ohun tí ọbabinrin Ṣeba fẹ́, tí ó tọrọ lọ́wọ́ Solomoni pátá ni Solomoni fún un, láìka ọpọlọpọ ẹ̀bùn tí wọ́n ti kọ́ fi ṣe é lálejò. Ọbabinrin náà pẹlu àwọn iranṣẹ rẹ̀ bá pada sí ilẹ̀ wọn. Ọtalelẹgbẹta ó lé mẹfa (666) ìwọ̀n talẹnti wúrà ni ó ń wọlé fún Solomoni ọba lọdọọdun, láìka èyí tí àwọn oníṣòwò ń san fún un, èyí tí ń wá láti ibi òwò rẹ̀, ati èyí tí àwọn ọba Arabia ati àwọn gomina ilẹ̀ Israẹli ń san. Solomoni ṣe igba (200) apata wúrà ńláńlá, wúrà tí ó lò fún ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹgbẹta (600) ìwọ̀n ṣekeli. Ó sì tún ṣe ọọdunrun (300) apata wúrà kéékèèké, wúrà tí ó lò fún ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìwọ̀n mina mẹta mẹta. Solomoni ọba kó gbogbo apata wọnyi sinu Ilé Igbó Lẹbanoni. Ó fi eyín erin ṣe ìtẹ́ ńlá kan, ó sì yọ́ wúrà dáradára bò ó. Ìtẹ́ náà ní àtẹ̀gùn mẹfa, ère orí ọmọ mààlúù sì wà lẹ́yìn ìtẹ́ náà. Ère kinniun wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji ibi tí wọn ń gbé apá lé lára ìtẹ́ náà. Ère kinniun mejila wà lórí àwọn àtẹ̀gùn mẹfẹẹfa, meji meji lórí àtẹ̀gùn kọ̀ọ̀kan, ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji àtẹ̀gùn náà; kò sí ìjọba orílẹ̀-èdè kankan tí ó tún ní irú ìtẹ́ náà. Wúrà ni wọ́n fi ṣe gbogbo ife ìmumi Solomoni, ati gbogbo àwọn ohun èlò tí ó wà ninu Ilé Igbó Lẹbanoni. Kò sí ẹyọ kan ninu wọn tí wọ́n fi fadaka ṣe, nítorí pé fadaka kò já mọ́ nǹkankan ní àkókò Solomoni. Ó ní ọpọlọpọ ọkọ̀ ojú omi Taṣiṣi tí wọ́n máa ń bá àwọn ọkọ̀ ojú omi Hiramu lọ sí òkè òkun. Ọdún kẹta kẹta ni wọ́n máa ń pada dé, wọn á sì máa kó ọpọlọpọ wúrà, ati fadaka, eyín erin, ìnàkí, ati ẹyẹ ọ̀kín bọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ọba ṣe lọ́rọ̀, tí ó sì gbọ́n ju gbogbo ọba yòókù lọ. Gbogbo aráyé a sì máa fẹ́ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, láti tẹ́tí sí ọgbọ́n tí Ọlọrun fún un. Ní ọdọọdún ni ọpọlọpọ eniyan máa ń mú ọpọlọpọ ẹ̀bùn àwọn nǹkan tí wọ́n fi fadaka ati wúrà ṣe wá sọ́dọ̀ rẹ̀, pẹlu ẹ̀wù, ati turari olóòórùn dídùn, ẹṣin, ati ìbaaka. Ọpọlọpọ kẹ̀kẹ́ ogun ati ẹlẹ́ṣin ni Solomoni ọba kó jọ, kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ jẹ́ egbeje (1,400), àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbaafa (1,200). Ó fi apá kan ninu wọn sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ ní Jerusalẹmu, ó sì kó àwọn yòókù sí ìlú ńláńlá tí ó ń kó àwọn kẹ̀kẹ́ ogun sí káàkiri. Solomoni ọba mú kí fadaka pọ̀ ní Jerusalẹmu bí òkúta, igi Kedari sì pọ̀ bí igi Sikamore tí ó wà káàkiri ní Ṣefela ní ẹsẹ̀ òkè Juda. Láti Ijipti ati Kue ni àwọn oníṣòwò Solomoni tií máa bá a ra àwọn ẹṣin wá. Ẹgbẹta (600) ìwọ̀n ṣekeli fadaka ni wọ́n máa ń ra kẹ̀kẹ́ ogun kan láti Ijipti, wọn a sì máa ra ẹṣin kan ní aadọjọ (150) ìwọ̀n ṣekeli fadaka. Àwọn oníṣòwò Solomoni níí máa ń tà wọ́n fún àwọn ọba ilẹ̀ Hiti ati àwọn ọba ilẹ̀ Siria. Ọpọlọpọ àwọn obinrin àjèjì ni Solomoni fẹ́, lẹ́yìn ọmọ Farao, ọba Ijipti, tí ó kọ́kọ́ fẹ́, ó tún fẹ́ ará Moabu ati ará Amoni, ará Edomu ati ará Sidoni, ati ará Hiti. Solomoni ọba fẹ́ wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli tẹ́lẹ̀, pé wọn kò gbọdọ̀ fẹ́ aya láàrin àwọn orílẹ̀-èdè náà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbọdọ̀ fi ọmọ fún wọn; kí àwọn orílẹ̀-èdè náà má baà mú kí ọkàn àwọn ọmọ Israẹli ṣí sọ́dọ̀ àwọn oriṣa wọn. Ẹẹdẹgbẹrin (700) ni àwọn obinrin ati ọmọ ọba tí Solomoni gbé níyàwó, ó sì tún ní ọọdunrun (300) obinrin mìíràn. Àwọn obinrin náà sì mú kí ọkàn rẹ̀ ṣí kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun. Nígbà tí Solomoni di àgbàlagbà, àwọn iyawo rẹ̀ mú kí ọkàn rẹ̀ ṣí kúrò lọ́dọ̀ OLUWA, ó ń bọ àwọn oriṣa àjèjì, kò sì ṣe olóòótọ́ sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀ mọ́, bíi Dafidi, baba rẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí bọ Aṣitoreti, oriṣa àwọn ará Sidoni ati oriṣa Milikomu, ohun ìríra tí àwọn ará Amoni ń bọ. Ohun tí Solomoni ṣe burú lójú OLUWA, kò sì jẹ́ olóòótọ́ sí i gẹ́gẹ́ bí Dafidi, baba rẹ̀. Ó kọ́ pẹpẹ ìrúbọ kan sí orí òkè ní ìhà ìlà oòrùn Jerusalẹmu fún oriṣa Kemoṣi, ohun ìríra tí àwọn ará Moabu ń bọ, ati fún oriṣa Moleki, ohun ìríra tí àwọn ará Amoni ń bọ. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe fún gbogbo àwọn iyawo àjèjì tí ó fẹ́, tí wọn ń sun turari, tí wọ́n sì ń rúbọ sí àwọn oriṣa wọn. Inú bí OLUWA sí Solomoni, nítorí pé, ọkàn rẹ̀ ti yipada kúrò lọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun Israẹli tí ó fara hàn án nígbà meji, tí ó sì pàṣẹ fún un nítorí ọ̀rọ̀ yìí pé kò gbọdọ̀ bọ oriṣa. Ṣugbọn kò pa òfin OLUWA mọ́. OLUWA bá sọ fún Solomoni pé, “Nítorí pé o ti ṣe ìfẹ́ ọkàn rẹ, o kò pa majẹmu mi mọ́, o kò sì tẹ̀lé ìlànà tí mo pa láṣẹ fún ọ, dájúdájú n óo gba ìjọba náà kúrò ní ọwọ́ rẹ, n óo sì fi fún ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ rẹ. Ṣugbọn nítorí ti Dafidi baba rẹ, n kò ní ṣe ohun tí mo fẹ́ ṣe yìí ní àkókò tìrẹ. Ọmọ rẹ ni n óo já ìjọba gbà mọ́ lọ́wọ́. Ṣugbọn n kò ní gba gbogbo ìjọba náà kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, n óo ṣẹ́ ẹ̀yà kan kù sí ọmọ rẹ lọ́wọ́, nítorí ti Dafidi iranṣẹ mi ati ìlú Jerusalẹmu tí mo ti yàn.” OLUWA bá mú kí Adadi dojú ọ̀tá kọ Solomoni; Adadi yìí jẹ́ ìran ọba ní ilẹ̀ àwọn ará Edomu. Ṣáájú àkókò yìí, nígbà tí Dafidi gbógun ti àwọn ará Edomu, tí ó sì ṣẹgun wọn, Joabu balogun rẹ̀ lọ sin àwọn tí wọ́n kú sógun, ó sì pa gbogbo àwọn ọmọkunrin Edomu; nítorí pé Joabu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wà ní ilẹ̀ Edomu fún oṣù mẹfa, títí tí ó fi pa gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Edomu run. Ṣugbọn Adadi ati díẹ̀ lára àwọn iranṣẹ baba rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ ará Edomu sá lọ sí ilẹ̀ Ijipti, Adadi kéré pupọ nígbà náà. Adadi ati àwọn iranṣẹ baba rẹ̀ wọnyi kúrò ní Midiani, wọ́n sì lọ sí Parani. Ní Parani yìí ni àwọn ọkunrin mìíràn ti para pọ̀ mọ́ wọn, tí gbogbo wọ́n sì jọ lọ sí Ijipti. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Farao, ọba Ijipti, ó fún Adadi ní ilé ati ilẹ̀, ó sì ń pèsè oúnjẹ fún un déédé. Adadi bá ojurere Farao ọba pàdé, ọba bá fi arabinrin ayaba Tapenesi, iyawo rẹ̀, fún Adadi kí ó fi ṣe aya. Arabinrin ayaba Tapenesi yìí bí ọmọkunrin kan fún Adadi, ó sọ orúkọ rẹ̀ ní Genubati. Inú ilé Farao ọba ni ayaba Tapenesi ti tọ́ ọmọ náà dàgbà, láàrin àwọn ọmọ ọba. Nígbà tí Adadi gbọ́ ní Ijipti pé Dafidi ọba ti kú, ati pé Joabu, balogun rẹ̀ náà ti kú, ó wí fún Farao pé, “Jẹ́ kí n pada lọ sí ìlú mi.” Farao bá bi í léèrè pé, “Kí lo fẹ́ tí o kò rí lọ́dọ̀ mi, tí o fi fẹ́ máa lọ sí ìlú rẹ?” Ṣugbọn Adadi dá a lóhùn pé, “Ṣá jẹ́ kí n máa lọ.” Ọlọrun tún mú kí Resoni ọmọ Eliada dojú ọ̀tá kọ Solomoni, sísá ni Resoni yìí sá kúrò lọ́dọ̀ Hadadeseri, ọba Soba, tí ó jẹ́ ọ̀gá rẹ̀. Lẹ́yìn tí Dafidi ti ṣẹgun Hadadeseri ọba, tí ó sì ti pa àwọn ará Siria tí wọ́n wà lẹ́yìn rẹ̀, Resoni di olórí àwọn ìgárá ọlọ́ṣà kan tí wọ́n kó ara wọn jọ, tí wọn ń gbé Damasku. Àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ bá fi jọba ní Damasku. Ọ̀tá gidi ni ó jẹ́ fún Israẹli ní ìgbà ayé Solomoni, ó sì ṣe jamba bí Hadadi ti ṣe. Ó kórìíra àwọn ọmọ Israẹli, òun sì ni ọba ilẹ̀ Siria. Ẹnìkan tí ó tún kẹ̀yìn sí Solomoni ni ọ̀kan ninu àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ tí ń jẹ́ Jeroboamu, ọmọ Nebati, ará Sereda, ninu ẹ̀yà Efuraimu, obinrin opó kan tí ń jẹ́ Serua ni ìyá rẹ̀. Ìdí tí ó fi kẹ̀yìn sí Solomoni nìyí: Nígbà tí Solomoni fi ń kún ilẹ̀ tí ó wà ní apá ìlà oòrùn Jerusalẹmu, tí ó sì ń tún odi ìlú náà kọ́, ó ṣe akiyesi Jeroboamu pé ó jẹ́ ọdọmọkunrin tí ó ní akitiyan. Nígbà tí Solomoni rí i bí ó ti ń ṣiṣẹ́ kára kára, ó fi ṣe olórí àwọn tí wọn ń kóni ṣiṣẹ́ tipátipá ní gbogbo agbègbè ẹ̀yà Manase ati Efuraimu. Ní ọjọ́ kan, Jeroboamu ń ti Jerusalẹmu lọ sí ìrìn àjò kan, wolii Ahija, láti Ṣilo sì pàdé òun nìkan lójú ọ̀nà, ninu pápá. Wolii Ahija bọ́ ẹ̀wù àwọ̀lékè tuntun tí ó wọ̀, ó ya á sí ọ̀nà mejila. Ó fún Jeroboamu ni mẹ́wàá ninu rẹ̀, ó ní, “Gba mẹ́wàá yìí sọ́wọ́, nítorí OLUWA Ọlọrun Israẹli ní kí n wí fún ọ pé, òun óo gba ìjọba kúrò lọ́wọ́ Solomoni òun óo sì fi ẹ̀yà mẹ́wàá fún ọ. Ṣugbọn yóo ku ẹ̀yà kan sí ọwọ́ Solomoni, nítorí ti Dafidi, iranṣẹ òun, ati nítorí Jerusalẹmu, ìlú tí òun yàn fún ara òun ninu gbogbo ilẹ̀ Israẹli. Nítorí pé, Solomoni ti kọ òun sílẹ̀, ó sì ń bọ Aṣitoreti, oriṣa àwọn ará Sidoni; ati Kemoṣi, oriṣa àwọn ará Moabu; ati Milikomu oriṣa àwọn ará Amoni. Solomoni kò máa rìn ní ọ̀nà òun OLUWA, kí ó máa ṣe rere, kí ó máa pa òfin òun mọ́, kí ó sì máa tẹ̀lé ìlànà òun bí Dafidi baba rẹ̀ ti ṣe. Sibẹsibẹ ó ní òun kò ní gba gbogbo ìjọba náà kúrò lọ́wọ́ Solomoni, òun óo fi sílẹ̀ láti máa ṣe ìjọba ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, nítorí ti Dafidi, iranṣẹ òun, ẹni tí òun yàn, tí ó pa òfin òun mọ́, tí ó sì tẹ̀lé ìlànà òun. Ṣugbọn òun óo gba ìjọba náà kúrò lọ́wọ́ ọmọ Solomoni, òun óo sì fún ọ ní ẹ̀yà mẹ́wàá. Òun óo fi ẹ̀yà kan sílẹ̀ fún ọmọ rẹ̀, kí ọ̀kan ninu arọmọdọmọ Dafidi, iranṣẹ òun, lè máa jọba nígbà gbogbo ní Jerusalẹmu, ìlú tí òun ti yàn fún ìjọ́sìn ní orúkọ òun. Ó ní ìwọ Jeroboamu ni òun óo mú, tí òun óo sì fi jọba ní Israẹli, o óo sì máa jọba lórí gbogbo agbègbè tí ó bá wù ọ́. Tí o bá fetí sí gbogbo ohun tí òun pa láṣẹ fún ọ, tí o sì ń rìn ní ọ̀nà òun, tí ò ń ṣe ohun tí ó tọ́ lójú òun, tí o pa òfin òun mọ́ tí o sì ń mú àṣẹ òun ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí Dafidi, iranṣẹ òun ti ṣe, ó ní òun óo wà pẹlu rẹ, arọmọdọmọ rẹ ni yóo máa jọba lẹ́yìn rẹ, òun óo fi ìdí ìjọba rẹ múlẹ̀ bí òun ti ṣe fún Dafidi; òun óo sì fi Israẹli fún ọ. Ó ní òun óo jẹ arọmọdọmọ Dafidi níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Solomoni, ṣugbọn kò ní jẹ́ títí ayé.” Nítorí ọ̀rọ̀ yìí, Solomoni ń wá ọ̀nà láti pa Jeroboamu, ṣugbọn Jeroboamu sá lọ sọ́dọ̀ Ṣiṣaki, ọba Ijipti, níbẹ̀ ni ó sì wà títí tí Solomoni fi kú. Àwọn nǹkan yòókù tí Solomoni ṣe: gbogbo iṣẹ́ rẹ̀, ati ọgbọ́n rẹ̀, ni a kọ sinu Ìwé Ìṣe Solomoni. Ogoji ọdún ni ó fi jọba lórí gbogbo Israẹli ní Jerusalẹmu. Nígbà tí ó kú, wọ́n sin ín sí ìlú Dafidi, baba rẹ̀, Rehoboamu, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Rehoboamu lọ sí Ṣekemu, nítorí pé gbogbo Israẹli ti péjọ níbẹ̀ láti fi jọba. Nígbà tí Jeroboamu ọmọ Nebati gbọ́ ìròyìn yìí ní Ijipti, (níbẹ̀ ni ó ń gbé láti ìgbà tí ó ti sá lọ fún Solomoni ọba), ó pada wá sílé láti Ijipti. Àwọn ọmọ Israẹli ranṣẹ pè é, òun ati gbogbo wọ́n sì tọ Rehoboamu lọ, wọ́n wí fún un pé, “Àjàgà wúwo ni Solomoni baba rẹ gbé bọ̀ wá lọ́rùn. Ṣugbọn bí o bá dín iṣẹ́ líle baba rẹ yìí kù, tí o sì mú kí ìgbé ayé rọ̀ wá lọ́rùn, a óo máa sìn ọ́.” Rehoboamu bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ máa lọ ná, lẹ́yìn ọjọ́ mẹta, ẹ pada wá gbọ́ èsì.” Àwọn eniyan náà bá pada lọ. Rehoboamu ọba bá lọ jíròrò pẹlu àwọn àgbààgbà tí wọ́n jẹ́ olùdámọ̀ràn Solomoni baba rẹ̀ nígbà ayé rẹ̀, ó bi wọ́n léèrè pé, “Irú ìdáhùn wo ni ó yẹ kí n fún àwọn eniyan wọnyi?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bí o bá ṣe bí iranṣẹ fún àwọn eniyan wọnyi lónìí, tí o sì sìn wọ́n, tí o sì fún wọn ní èsì rere sí ìbéèrè tí wọ́n bèèrè lọ́wọ́ rẹ, ìwọ ni wọn óo máa sìn títí lae.” Ṣugbọn ó kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbààgbà fún un. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jíròrò pẹlu àwọn ọdọmọkunrin, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí wọ́n jọ dàgbà pọ̀, tí wọ́n wà ní ààfin pẹlu rẹ̀. Ó bi wọ́n léèrè, ó ní, “Kí ni ìmọ̀ràn tí ẹ lè gbà mí, lórí irú ìdáhùn tí a le fún àwọn eniyan tí wọ́n ní kí n dín ẹrù wúwo tí baba mi dì lé àwọn lórí kù?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ohun tí o óo wí fún àwọn tí wọ́n ní baba rẹ di ẹrù wúwo lé àwọn lórí, ṣugbọn kí o bá àwọn dín ẹrù yìí kù ni pé ìka ọwọ́ rẹ tí ó kéré jùlọ tóbi ju ẹ̀gbẹ́ baba rẹ lọ. Sọ fún wọn pé, ‘Ṣé ẹ sọ pé ẹrù wúwo ni baba mi dì rù yín? Tèmi tí n óo dì rù yín yóo tilẹ̀ tún wúwo jù bẹ́ẹ̀ lọ; ati pé ẹgba ni baba mi fi ń nà yín, ṣugbọn àkeekèé ni n óo máa fi ta yín.’ ” Jeroboamu ati gbogbo àwọn eniyan náà bá pada wá sọ́dọ̀ Rehoboamu ní ọjọ́ kẹta, gẹ́gẹ́ bí ó ti pàṣẹ fún wọn. Rehoboamu gbójú mọ́ àwọn eniyan náà bí ó ti ń dá wọn lóhùn, ó kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbààgbà fún un, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọdọmọkunrin ti gbà á nímọ̀ràn. Ó ní, “Ẹrù wúwo ni ẹ sọ pé baba mi dì rù yín, ṣugbọn èmi yóo tilẹ̀ tún dì kún un ni. Ẹgba ni ó fi nà yín, ṣugbọn àkeekèé ni n óo máa fi ta yín.” Nítorí náà, ọba kò gbọ́ ti àwọn eniyan náà, nítorí pé OLUWA alára ni ó fẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí rí bẹ́ẹ̀, kí ọ̀rọ̀ OLUWA lè ṣẹ, tí ó bá Jeroboamu ọmọ Nebati sọ, láti ẹnu wolii Ahija ará Ṣilo. Nígbà tí gbogbo Israẹli rí i pé, ọba kò gbọ́ tiwọn, wọ́n dá a lóhùn pé, “Kí ló kàn wá pẹlu ìdílé Dafidi? Kí ló dà wá pọ̀ pẹlu ọmọ Jese? Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ pada sílé yín, kí Dafidi máa bojútó ilé rẹ̀!” Gbogbo Israẹli bá pada sílé wọn; ṣugbọn Rehoboamu ń jọba lórí àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Juda. Lẹ́yìn náà, Rehoboamu ọba rán Adoniramu, tí ó jẹ́ ọ̀gá àgbà àwọn tí wọn ń kó àwọn eniyan ṣiṣẹ́ tipátipá, láti lọ bá àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì sọ ọ́ ní òkúta pa. Rehoboamu bá múra kíá, ó bọ́ sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó sá lọ sí Jerusalẹmu. Láti ìgbà náà ni Israẹli ti ń bá ìdílé Dafidi ṣọ̀tẹ̀ títí di òní yìí. Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ pé Jeroboamu ti pada dé láti ilẹ̀ Ijipti, wọ́n pè é sí ibi ìpàdé kan tí wọ́n ṣe, wọ́n sì fi jọba Israẹli. Kò sí ẹni tí ó tẹ̀lé ìdílé Dafidi, àfi ẹ̀yà Juda nìkan ṣoṣo. Nígbà tí Rehoboamu pada dé Jerusalẹmu, ó ṣa ọ̀kẹ́ mẹsan-an (180,000) ọmọ ogun tí wọ́n jẹ́ akikanju jùlọ láti inú ẹ̀yà Juda ati ti Bẹnjamini, láti lọ gbógun ti ilé Israẹli kí wọ́n sì gba ìjọba ìhà àríwá Israẹli pada fún un. Ṣugbọn Ọlọrun sọ fún wolii Ṣemaaya, pé kí ó jíṣẹ́ fún Rehoboamu, ọba Juda ati gbogbo ẹ̀yà Juda ati ti Bẹnjamini, pé OLUWA ni wọn kò gbọdọ̀ gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli, nítorí pé arakunrin wọn ni wọ́n, ati pé kí olukuluku pada sí ilé rẹ̀, nítorí pé ìfẹ́ òun Ọlọrun ni ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ yìí. Nítorí náà gbogbo wọ́n gba ohun tí OLUWA pa láṣẹ, wọ́n sì pada sí ilé wọn bí OLUWA ti wí. Jeroboamu ọba Israẹli mọ odi yí ìlú Ṣekemu, tí ó wà ní agbègbè olókè ti Efuraimu ká, ó sì ń gbé ibẹ̀. Lẹ́yìn náà, láti Ṣekemu ó lọ mọ odi yí ìlú Penueli ká. Nígbà tí ó yá, ó rò ninu ara rẹ̀ pé, “Ìjọba yìí yóo pada di ti ilé Dafidi.” Ó ní, “Bí àwọn eniyan wọnyi bá ń lọ rúbọ ní ilé OLUWA ní Jerusalẹmu, ọkàn gbogbo wọ́n lè tipa bẹ́ẹ̀ pada sẹ́yìn Rehoboamu, oluwa wọn; wọn óo sì pa mí, wọn óo sì pada tọ Rehoboamu, ọba Juda, lọ.” Jeroboamu lọ gba àmọ̀ràn, ó bá fi wúrà yá ère akọ mààlúù meji, ó sì wí fún àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ó pẹ́ tí ẹ ti ń lọ rúbọ ní Jerusalẹmu. Ó tó gẹ́ẹ́! Ọlọrun yín, tí ó ko yín jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti nìyí.” Ó gbé ọ̀kan kalẹ̀ ní ìlú Bẹtẹli ó sì gbé ekeji sí ìlú Dani. Ọ̀rọ̀ yìí di ẹ̀ṣẹ̀ sí wọn lọ́rùn nítorí pé àwọn eniyan náà bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí ìlú Bẹtẹli ati ìlú Dani láti jọ́sìn. Jeroboamu tún kọ́ àwọn pẹpẹ ìrúbọ sí orí òkè káàkiri, ó sì yan àwọn eniyan ninu gbogbo ìdílé tí kì í ṣe ìran ẹ̀yà Lefi, láti máa ṣiṣẹ́ alufaa. Jeroboamu ya ọjọ́ kẹẹdogun oṣù kẹjọ sọ́tọ̀ fún àjọ̀dún, gẹ́gẹ́ bí àjọ̀dún ilẹ̀ Juda, ó sì rúbọ lórí pẹpẹ sí akọ mààlúù tí ó fi wúrà ṣe ní ìlú Bẹtẹli. Ó fi àwọn alufaa kan sibẹ, láti máa ṣe iṣẹ́ alufaa ninu àwọn ilé ìsìn tí ó kọ́ sibẹ. Ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù kẹjọ tíí ṣe ọjọ́ tí ó yàn fún ara rẹ̀, ó lọ sí ibi pẹpẹ tí ó kọ́ sí ìlú Bẹtẹli láti rúbọ. Ó yan àjọ̀dún fún àwọn ọmọ Israẹli, ó sì lọ sun turari lórí pẹpẹ. OLUWA pàṣẹ fún wolii kan, ará Juda, pé kí ó lọ sí Bẹtẹli; nígbà tí ó débẹ̀ ó bá Jeroboamu tí ó dúró níwájú pẹpẹ láti sun turari. Wolii náà bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ sí pẹpẹ náà, ó ní, “Ìwọ pẹpẹ yìí, ìwọ pẹpẹ yìí, gbọ́ ohun tí OLUWA wí, ó ní, ‘Wò ó! A óo bí ọmọ kan ninu ìdílé Dafidi, orúkọ rẹ̀ yóo máa jẹ́ Josaya. Lórí ìwọ pẹpẹ yìí ni yóo ti fi àwọn alufaa oriṣa tí ń sun turari lórí rẹ rúbọ. A óo sì máa sun egungun eniyan lórí rẹ.’ ” Ó sì fún wọn ní àmì kan ní ọjọ́ náà, tí wọn yóo fi mọ̀ pé OLUWA ni ó gba ẹnu òun sọ̀rọ̀. Ó ní, “Pẹpẹ yìí yóo wó lulẹ̀, eérú orí rẹ̀ yóo sì fọ́n dànù.” Nígbà tí Jeroboamu gbọ́ ìkìlọ̀ tí wolii Ọlọrun yìí ṣe fún pẹpẹ náà, ó na ọwọ́ sí wolii náà láti ibi pẹpẹ, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n mú un. Lẹsẹkẹsẹ, ọwọ́ ọba bá gan, kò sì lè gbé e wálẹ̀ mọ́. Pẹpẹ náà wó lulẹ̀, eérú orí rẹ̀ sì fọ́n dànù gẹ́gẹ́ bí wolii náà ti sọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ OLUWA. Jeroboamu ọba bẹ wolii náà pé, “Jọ̀wọ́, bẹ OLUWA Ọlọrun rẹ, kí o sì gbadura sí i pé kí ó wo apá mi sàn.” Wolii náà bá gbadura sí OLUWA, apá Jeroboamu ọba sì sàn, ó pada sí bí ó ti wà tẹ́lẹ̀. Ọba bá sọ fún wolii náà pé, “Jẹ́ kí á lọ sí ilé mi kí o lọ jẹun, n óo sì fún ọ ní ẹ̀bùn fún ohun tí o ṣe fún mi.” Ṣugbọn wolii náà dáhùn pé, “Bí o bá tilẹ̀ fẹ́ fún mi ní ìdajì ohun tí o ní, n kò ní bá ọ lọ, n kò ní fi ẹnu kan nǹkankan ní ilẹ̀ yìí. Nítorí pé, OLUWA ti pàṣẹ fún mi pé n kò gbọdọ̀ fẹnu kan nǹkankan ati pé, n kò gbọdọ̀ gba ọ̀nà tí mo gbà wá pada.” Nítorí náà, kò gba ọ̀nà ibi tí ó gbà wá pada, ọ̀nà ibòmíràn ni ó gbà lọ. Wolii àgbàlagbà kan wà ní ìlú Bẹtẹli ní ìgbà náà. Àwọn ọmọ wolii náà lọ sọ ohun tí wolii tí ó wá láti Juda ṣe ní Bẹtẹli ní ọjọ́ náà fún baba wọn, ati ohun tí ó sọ fún Jeroboamu ọba. Wolii àgbàlagbà náà bá bi wọ́n pé, “Ọ̀nà ibo ni ó gbà lọ?” Wọ́n sì fi ọ̀nà náà hàn án. Ó sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé kí wọ́n di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ òun ní gàárì, wọ́n di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì. Ó bá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ gùn, ó bẹ̀rẹ̀ sí lépa wolii ará Juda náà. Ó bá a níbi tí ó jókòó sí lábẹ́ igi Oaku kan, ó bi í pé, ṣe òun ni wolii tí ó wá láti Juda? Ọkunrin náà sì dá a lóhùn pé òun ni. Wolii àgbàlagbà yìí bá wí fún un pé, “Bá mi kálọ sílé, kí o lọ jẹun.” Ṣugbọn wolii ará Juda náà dáhùn pé, “N kò gbọdọ̀ bá ọ pada lọ sí ilé rẹ, bẹ́ẹ̀ ni n kò gbọdọ̀ fi ẹnu kan nǹkankan ní ilẹ̀ yìí. Nítorí OLUWA ti pàṣẹ fún mi pé, n kò gbọdọ̀ fi ẹnu kan ohunkohun; ati pé, ọ̀nà tí mo bá gbà wá síbí, n kò gbọdọ̀ gbà á pada lọ sílé.” Wolii àgbàlagbà, ará Bẹtẹli náà bá purọ́ fún un pé, “Wolii bíi rẹ ni èmi náà. OLUWA ni ó sì pàṣẹ fún angẹli kan tí ó sọ fún mi pé kí n mú ọ lọ sí ilé, kí n sì fún ọ ní oúnjẹ ati omi.” Wolii ará Juda yìí bá bá wolii àgbàlagbà náà pada lọ sí ilé rẹ̀, ó sì jẹun níbẹ̀. Bí wọ́n ti jóòkó tí wọn ń jẹun, OLUWA bá wolii àgbàlagbà tí ó pè é pada sọ̀rọ̀. Ó bá kígbe mọ́ wolii ará Juda yìí, ó ní, “OLUWA ní, nítorí pé o ti ṣe àìgbọràn sí òun, o kò sì ṣe ohun tí òun OLUWA Ọlọrun rẹ pa láṣẹ fún ọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, o pada, o jẹ, o sì mu ní ibi tí òun ti pàṣẹ pé o kò gbọdọ̀ fi ẹnu kan nǹkankan. Nítorí náà, o óo kú, wọn kò sì ní sin òkú rẹ sinu ibojì àwọn baba rẹ.” Nígbà tí wọ́n jẹun tan, wolii àgbàlagbà yìí di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan ní gàárì fún wolii ará Juda. Wolii ará Juda náà bá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ gùn, ó ń lọ. Bí ó ti ń lọ lójú ọ̀nà, kinniun kan yọ sí i, ó sì pa á. Òkú rẹ̀ wà ní ojú ọ̀nà níbẹ̀, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati kinniun náà sì dúró tì í. Àwọn ọkunrin kan tí wọn ń kọjá lọ rí òkú ọkunrin yìí lójú ọ̀nà, ati kinniun tí ó dúró tì í. Wọ́n lọ sí ìlú Bẹtẹli níbi tí wolii àgbàlagbà náà ń gbé, wọ́n sì ròyìn ohun tí wọ́n rí fún un. Nígbà tí wolii àgbàlagbà náà gbọ́, ó ní, “Wolii tí ó ṣàìgbọràn sí ọ̀rọ̀ OLUWA ni. Nítorí náà ni OLUWA fi rán kinniun sí i, pé kí ó pa á, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti kìlọ̀ fún un tẹ́lẹ̀.” Ó bá pe àwọn ọmọ rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ bá mi di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mi ní gàárì.” Wọ́n sì bá a di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì. Ó bá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ gùn, ó gbọ̀nà, ó sì rí òkú wolii náà nílẹ̀ lójú ọ̀nà, níbi tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati kinniun náà ti dúró tì í. Kinniun yìí kò jẹ òkú rẹ̀ rárá bẹ́ẹ̀ ni kò sì ṣe kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní ohunkohun. Wolii àgbàlagbà yìí gbé òkú ọkunrin náà sí ẹ̀yìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ó sì gbé e pada wá sí ìlú Bẹtẹli láti ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, ati láti sin ín. Ninu ibojì tirẹ̀ gan-an ni ó sin ín sí. Òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, ó ní, “Ó ṣe, arakunrin mi! Arakunrin mi!” Lẹ́yìn ìsìnkú náà, wolii àgbàlagbà yìí sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, nígbà tí òun bá kú, inú ibojì kan náà ni kí wọn ó sin òun sí, ati pé ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ gan-an ni kí wọ́n tẹ́ òkú òun sí. Ó ní, “Nítòótọ́, ọ̀rọ̀ ìbáwí tí OLUWA pàṣẹ pé kí ó sọ sí pẹpẹ Bẹtẹli, ati gbogbo pẹpẹ ìrúbọ tí ó wà káàkiri ní àwọn ìlú Samaria yóo ṣẹ.” Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọnyi, Jeroboamu, ọba Israẹli kò yipada kúrò ninu ìwà burúkú rẹ̀. Ṣugbọn ó ń yan ẹnikẹ́ni tí ó bá wù ú láàrin àwọn eniyan ó sì ń fi wọ́n jẹ alufaa ní àwọn ibi pẹpẹ ìrúbọ káàkiri. Ẹ̀ṣẹ̀ ni ohun tí ó ṣe yìí, ẹ̀ṣẹ̀ yìí ni ó sì run ìran rẹ̀ lórí oyè, tí wọ́n fi parun patapata lórílẹ̀ ayé. Ní àkókò yìí Abija, ọmọ Jeroboamu ọba ṣàìsàn, Jeroboamu wí fún aya rẹ̀ pé, “Dìde, kí o yíra pada, kí ẹnikẹ́ni má lè dá ọ mọ̀ pé aya ọba ni ọ́. Lọ sí Ṣilo níbi tí wolii Ahija tí ó wí fún mi pé n óo jọba Israẹli, ń gbé. Mú burẹdi mẹ́wàá, àkàrà dídùn díẹ̀, ati ìgò oyin kan lọ́wọ́ fún un, yóo sì sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ọmọ náà fún ọ.” Aya Jeroboamu sì ṣe bí Jeroboamu ti wí. Ó lọ sí ilé wolii Ahija ní Ṣilo. Ogbó ti dé sí Ahija ní àkókò yìí, kò sì ríran mọ́, ṣugbọn OLUWA ti sọ fún un pé aya Jeroboamu ń bọ̀ wá bèèrè ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ọmọ rẹ̀ tí ó ń ṣàìsàn, OLUWA sì ti sọ ohun tí Ahija yóo sọ fún un. Nígbà tí aya Jeroboamu dé, ó ṣe bí ẹni pé ẹlòmíràn ni. Ṣugbọn bí Ahija ti gbúròó rẹ̀ tí ó ń wọlé bọ̀ ní ẹnu ọ̀nà, ó ní, “Wọlé, ìwọ aya Jeroboamu. Kí ló dé tí o fi ń ṣe bí ẹni pé ẹlòmíràn ni ọ́? Ìròyìn burúkú ni mo ní fún ọ. Lọ sọ fún Jeroboamu pé, ‘OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, “Mo gbé ọ ga láàrin àwọn eniyan náà, mo sì fi ọ́ jọba lórí Israẹli, àwọn eniyan mi. Mo gba ìjọba lọ́wọ́ ìdílé Dafidi, mo sì fún ọ, o kò ṣe bíi Dafidi, iranṣẹ mi, tí ó pa òfin mi mọ́, tí ó sìn mí tọkàntọkàn, tí ó sì ṣe kìkì ohun tí ó dára lójú mi. Ṣugbọn o ti dá ọpọlọpọ ẹ̀ṣẹ̀ burúkú ju ti àwọn tí wọ́n jọba ṣáájú rẹ lọ. O yá ère, o sì dá oniruuru oriṣa láti máa sìn, o mú mi bínú, o sì ti pada lẹ́yìn mi. Nítorí náà, n óo jẹ́ kí ibi bá ìdílé rẹ, n óo sì pa gbogbo ọkunrin inú ìdílé rẹ run, àtẹrú àtọmọ. Bí ìgbà tí eniyan bá sun pàǹtí, tí ó sì jóná ráúráú ni n óo pa gbogbo ìdílé rẹ run. Ajá ni yóo jẹ òkú ẹnikẹ́ni ninu ìdílé rẹ tí ó bá kú láàrin ìlú; ẹni tí ó bá sì kú sinu igbó, ẹyẹ ni yóo jẹ òkú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA wí.” ’ “Nítorí náà, dìde kí o pada sílé, ṣugbọn bí o bá ti ń wọ ìlú, bẹ́ẹ̀ ni ọmọ náà yóo kú. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni yóo ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, wọn yóo sì sin ín, nítorí òun nìkan ni wọ́n óo sin ninu ìdílé Jeroboamu, nítorí òun nìkan ni inú OLUWA Ọlọrun Israẹli dùn sí. OLUWA yóo fi ẹnìkan jọba lórí Israẹli tí yóo run ìdílé Jeroboamu lónìí, àní láti ìsinsìnyìí lọ. OLUWA yóo jẹ àwọn ọmọ Israẹli níyà, wọn óo sì máa gbọ̀n bí ewé ojú omi. OLUWA yóo fà wọ́n tu kúrò ninu ilẹ̀ dáradára tí ó fún àwọn baba ńlá wọn, yóo sì fọ́n wọn káàkiri òdìkejì odò Yufurate, nítorí ère oriṣa Aṣerimu tí wọ́n ṣe tí ó mú OLUWA bínú. Yóo kọ Israẹli sílẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí Jeroboamu dá ati èyí tí ó mú kí Israẹli dá pẹlu.” Aya Jeroboamu bá gbéra, ó pada sí Tirisa. Bí ó ti fẹ́ wọlé ni ọmọ tí ń ṣàìsàn náà kú. Àwọn ọmọ Israẹli sin ín, wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ bí ọ̀rọ̀ tí OLUWA gba ẹnu wolii Ahija, iranṣẹ rẹ̀ sọ. Gbogbo àwọn nǹkan yòókù tí Jeroboamu ọba ṣe: àwọn ogun tí ó jà, ati bí ó ti ṣe ṣe ìjọba rẹ̀, gbogbo rẹ̀ wà ninu ìwé àkọsílẹ̀ Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. Jeroboamu jọba fún ọdún mejilelogun. Lẹ́yìn náà, ó kú, wọ́n sì sin ín. Nadabu, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Ẹni ọdún mọkanlelogoji ni Rehoboamu ọmọ Solomoni nígbà tí ó gun orí oyè ní ilẹ̀ Juda, ọdún mẹtadinlogun ni ó fi jọba ní Jerusalẹmu, ìlú tí OLUWA yàn láàrin gbogbo ilẹ̀ Israẹli fún ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ̀. Naama ará Amoni ni ìyá rẹ̀. Àwọn ẹ̀yà Juda ṣẹ̀ sí OLUWA, wọ́n sì ṣe ohun tí ó mú un bínú lọpọlọpọ ju gbogbo àwọn baba ńlá wọn lọ. Nítorí wọ́n kọ́ pẹpẹ ìrúbọ, wọ́n sì ri ọ̀wọ̀n òkúta ati ère oriṣa Aṣerimu mọ́lẹ̀ lórí gbogbo òkè ati lábẹ́ igi tútù káàkiri. Àwọn ọkunrin tí wọ́n sọ ara wọn di aṣẹ́wó ní ojúbọ àwọn oriṣa náà sì pọ̀ ní ilẹ̀ náà. Gbogbo ohun ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA lé jáde fún àwọn ọmọ Israẹli ń ṣe, ni àwọn náà ń ṣe. Ní ọdún karun-un ìjọba Rehoboamu, Ṣiṣaki, ọba Ijipti, gbógun ti Jerusalẹmu. Ó kó gbogbo ìṣúra tí ó wà ninu ilé OLUWA ati ti ààfin ọba pátá; gbogbo apata wúrà tí Solomoni ṣe ni ó kó lọ pẹlu. Rehoboamu bá ṣe apata idẹ dípò wọn. Ó sì fi àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ tí ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ààfin ọba ṣe alabojuto wọn. Nígbàkúùgbà tí ọba bá ń lọ sinu ilé OLUWA, àwọn ẹ̀ṣọ́ á gbé apata náà tẹ̀lé e, wọn á sì dá wọn pada sinu ilé ìṣúra lọ́dọ̀ àwọn ẹ̀ṣọ́. Gbogbo àwọn nǹkan yòókù tí Rehoboamu ọba ṣe ni a kọ sílẹ̀ ninu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. Ní gbogbo ìgbà ayé Rehoboamu ati ti Jeroboamu ni àwọn mejeeji í máa gbógun ti ara wọn. Rehoboamu jáde láyé, wọ́n sì sin ín sinu ibojì ọba, ní ìlú Dafidi. Naama ará Amoni ni ìyá rẹ̀. Abijamu ọmọ rẹ̀ ni ó sì gun orí oyè lẹ́yìn rẹ̀. Ní ọdún kejidinlogun tí Jeroboamu jọba Israẹli, ni Abijamu gorí oyè ní ilẹ̀ Juda. Ọdún mẹta ló fi jọba ní Jerusalẹmu. Maaka ọmọ Absalomu ni ìyá rẹ̀. Gbogbo irú ẹ̀ṣẹ̀ tí baba Abijamu dá, ni òun náà dá. Kò fi tọkàntọkàn ṣe olóòótọ́ sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀ bí Dafidi, baba ńlá rẹ̀ ti ṣe. Sibẹsibẹ, nítorí ti Dafidi, OLUWA Ọlọrun fún Abijamu ní ọmọkunrin kan tí ó gorí oyè lẹ́yìn rẹ̀, ní Jerusalẹmu, tí ó sì dáàbò bo Jerusalẹmu. Ìdí rẹ̀ ni pé, Dafidi ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA, kò sì ṣàìgbọràn sí àṣẹ rẹ̀ rí ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, (àfi ohun tí ó ṣe sí Uraya ará Hiti). Ogun tí ó wà láàrin Rehoboamu ati Jeroboamu tún wà bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ìgbà tí Abijamu wà lórí oyè. Gbogbo àwọn nǹkan yòókù tí Abijamu ṣe wà ninu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. Ogun si wà láàrin Abijah ati Jeroboamu. Abijamu jáde láyé, wọ́n sì sin ín ní ìlú Dafidi, Asa, ọmọ rẹ̀ sì gorí oyè lẹ́yìn rẹ̀. Nígbà tí ó di ogún ọdún tí Jeroboamu ti jọba Israẹli ni Asa gorí oyè ní ilẹ̀ Juda. Ọdún mọkanlelogoji ni ó fi jọba ní Jerusalẹmu. Maaka ọmọ Absalomu ni ìyá baba rẹ̀. Asa ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA gẹ́gẹ́ bíi Dafidi baba ńlá rẹ̀. Gbogbo àwọn aṣẹ́wó ọkunrin tí wọ́n wà ní ojúbọ àwọn oriṣa káàkiri ní ilẹ̀ Juda, ni Asa lé jáde kúrò ni ilẹ̀ náà; ó sì kó gbogbo àwọn oriṣa tí àwọn baba ńlá rẹ̀ ti ṣe dànù. Ó yọ Maaka, ìyá baba rẹ̀, kúrò lórí oyè ìyá ọba, nítorí pé Maaka yá ère tí ó tini lójú kan fún oriṣa Aṣera. Asa gé oriṣa náà lulẹ̀, ó sì dáná sun ún ní àfonífojì Kidironi. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Asa kò pa gbogbo àwọn ojúbọ oriṣa wọn run, ó jẹ́ olóòótọ́ sí OLUWA ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. Gbogbo àwọn ohun èlò pẹlu wúrà ati fadaka tí baba rẹ̀ ti yà sọ́tọ̀ fún OLUWA, ati àwọn tí òun pàápàá yà sọ́tọ̀, ni ó dá pada sinu ilé OLUWA. Nígbà gbogbo ni Asa ọba Juda, ati Baaṣa, ọba Israẹli ń gbógun ti ara wọn, ní gbogbo ìgbà tí wọ́n wà lórí oyè. Baaṣa gbógun ti ilẹ̀ Juda, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mọ odi yí Rama po, kí ẹnikẹ́ni má baà rí ààyè lọ sí ọ̀dọ̀ Asa, ọba Juda, tabi kí ẹnikẹ́ni jáde kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Asa ọba bá kó gbogbo fadaka ati wúrà tí ó kù ninu ilé ìṣúra ní ilé OLUWA ati ti ààfin ọba jọ, ó kó wọn rán àwọn iranṣẹ rẹ̀ sí Benhadadi ọmọ Tabirimoni, ọmọ Hesioni, ọba ilẹ̀ Siria, tí ó wà ní ìlú Damasku. Asa ní kí wọ́n wí fún Benhadadi, pé, “Jẹ́ kí a ní àjọṣepọ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti ṣe; gba wúrà ati fadaka tí mo fi ranṣẹ sí ọ yìí, kí o dẹ́kun àjọṣepọ̀ rẹ pẹlu Baaṣa ọba Israẹli, kí ó lè kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kúrò lórí ilẹ̀ mi.” Benhadadi ọba gba ohun tí Asa wí, ó sì rán àwọn ọ̀gágun rẹ̀ láti lọ gbógun ti àwọn ìlú ńláńlá Israẹli. Wọ́n gba ìlú Ijoni ati Dani, Abeli Beti Maaka, ati gbogbo agbègbè Kineroti, pẹlu gbogbo agbègbè Nafutali. Nígbà tí Baaṣa gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó dáwọ́ odi tí ó ń mọ yí Rama dúró, ó sì ń gbé Tirisa. Asa ọba bá kéde ní gbogbo ilẹ̀ Juda, ó ní kí gbogbo eniyan patapata láìku ẹnìkan, lọ kó gbogbo òkúta ati igi ti Baaṣa fi ń mọ odi Rama kúrò ní Rama. Igi ati òkúta náà ni Asa fi mọ odi ìlú Geba tí ó wà ní ilẹ̀ Bẹnjamini, ati ti ìlú Misipa. Gbogbo nǹkan yòókù tí Asa ọba ṣe, ati àwọn ìwà akin tí ó hù, ati àwọn ìlú tí ó mọ odi yípo, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda, ṣugbọn ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, nǹkankan mú un lẹ́sẹ̀. Asa jáde láyé, wọ́n sì sin ín sí ibojì àwọn ọba ní ìlú Dafidi. Jehoṣafati, ọmọ rẹ̀ sì gorí oyè lẹ́yìn rẹ̀. Ní ọdún keji tí Asa jọba ní Juda, ni Nadabu, ọmọ Jeroboamu, gorí oyè ní ilẹ̀ Israẹli, ó sì jọba fún ọdún meji. Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ọ̀nà baba rẹ̀, ó sì dá irú ẹ̀ṣẹ̀ tí baba rẹ̀ mú kí Israẹli dá. Baaṣa, ọmọ Ahija, láti inú ẹ̀yà Isakari, ṣọ̀tẹ̀ sí Nadabu, ó sì pa á ní ìlú Gibetoni, ní ilẹ̀ Filistia, nígbà tí Nadabu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti ìlú náà. Ní ọdún kẹta tí Asa gorí oyè ní ilẹ̀ Juda, ni Baaṣa pa Nadabu. Baaṣa gorí oyè dípò Nadabu, ó sì di ọba ilẹ̀ Israẹli. Lẹsẹkẹsẹ tí Baaṣa gorí oyè ni ó bẹ̀rẹ̀ sí pa gbogbo ìdílé Jeroboamu. Gbogbo ìran Jeroboamu pátá ni Baaṣa pa láìku ẹyọ ẹnìkan, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí OLUWA ti sọ láti ẹnu iranṣẹ rẹ̀, wolii Ahija, ará Ṣilo. Nítorí Jeroboamu ṣe ohun tí ó bí OLUWA Ọlọrun Israẹli ninu: ó dẹ́ṣẹ̀, ó sì mú kí Israẹli náà dẹ́ṣẹ̀. Gbogbo nǹkan yòókù tí Nadabu ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. Ní gbogbo àsìkò tí Asa ọba Juda ati Baaṣa ọba Israẹli wà lórí oyè, ogun ni wọ́n ń bá ara wọn jà. Ní ọdún kẹta tí Asa, ọba Juda, gorí oyè, ni Baaṣa, ọmọ Ahija, gorí oyè, ní ìlú Tirisa, ó sì di ọba gbogbo Israẹli. Ó jọba fún ọdún mẹrinlelogun. Ó ṣe nǹkan tó burú lójú OLUWA, ó rìn ní ọ̀nà Jeroboamu, ó sì dá ẹ̀ṣẹ̀ tí Jeroboamu mú kí Israẹli dá. Ọlọrun rán wolii Jehu, ọmọ Hanani, pé kí ó sọ fún Baaṣa ọba pé, “O kò jámọ́ nǹkankan tẹ́lẹ̀, kí n tó fi ọ́ ṣe olórí àwọn ọmọ Israẹli, eniyan mi. Ṣugbọn irú ìgbésẹ̀ tí Jeroboamu gbé ni ìwọ náà gbé, ìwọ náà mú kí àwọn eniyan mi dẹ́ṣẹ̀; ẹ̀ṣẹ̀ wọn sì ti mú mi bínú gidigidi. Nítorí náà, n óo pa ìwọ ati ìdílé rẹ rẹ́. Bí mo ti ṣe ìdílé Jeroboamu, bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe ìdílé tìrẹ náà. Ẹnikẹ́ni ninu ìdílé rẹ tí ó bá kú láàrin ìlú, ajá ni yóo jẹ òkú rẹ̀, èyíkéyìí ninu wọn tí ó bá sì kú sinu igbó, àwọn ẹyẹ ni yóo jẹ òkú rẹ̀.” Gbogbo nǹkan yòókù tí Baaṣa ṣe, ati gbogbo iṣẹ́ akikanju rẹ̀, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. Baaṣa kú, wọ́n sì sin ín sí Tirisa. Ela ọmọ rẹ̀ sì gorí oyè lẹ́yìn rẹ̀. Lẹ́yìn náà OLUWA ti ẹnu wolii Jehu ọmọ Hanani bá Baaṣa ati ìdílé rẹ̀ wí nítorí gbogbo ibi tí ó ṣe lójú OLUWA, tí ó fi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ mú OLUWA bínú nítorí pé ó dẹ́ṣẹ̀ bíi Jeroboamu, ati pé òun ló tún pa ìdílé Jeroboamu run. Ní ọdún kẹrindinlọgbọn tí Asa jọba ní Juda, ni Ela, ọmọ Baaṣa, gorí oyè ní ilẹ̀ Israẹli; ó sì jọba ní Tirisa fún ọdún meji. Simiri, ọ̀kan ninu àwọn ọ̀gágun rẹ̀, alabojuto ìdajì àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ṣọ̀tẹ̀ sí i. Ní ọjọ́ kan, níbi tí ó ti ń mu ọtí àmupara ní ilé Arisa, alabojuto ààfin, ní Tirisa, ní ọdún kẹtadinlọgbọn tí Asa ọba Juda gorí oyè, Simiri bá wọlé, ó fi idà ṣá Ela pa, ó bá fi ara rẹ̀ jọba dípò Ela. Bí Simiri ti gorí oyè, tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba ni ó pa gbogbo àwọn ìdílé Baaṣa patapata. Gbogbo àwọn ìbátan ati ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọkunrin ni ó pa láìdá ẹnikẹ́ni sí. Báyìí ni Simiri ṣe pa gbogbo ìdílé Baaṣa, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀, láti ẹnu wolii Jehu, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí Baaṣa ati Ela ọmọ rẹ̀ dá ati èyí tí wọ́n mú kí Israẹli dá, tí wọ́n mú kí OLUWA Ọlọrun Israẹli bínú nítorí oriṣa wọn. Gbogbo nǹkan yòókù tí Ela ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. Ní ọdún kẹtadinlọgbọn tí Asa jọba ní Juda, Simiri gorí oyè ní Tirisa, ó sì jọba Israẹli fún ọjọ́ meje. Ní àkókò yìí àwọn ọmọ ogun Israẹli gbógun ti ìlú Gibetoni ní ilẹ̀ Filistia. Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé, Simiri ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọba ati pé ó ti pa á, lẹsẹkẹsẹ ni gbogbo Israẹli fi Omiri olórí ogun, jọba Israẹli ninu àgọ́ wọn ní ọjọ́ náà. Omiri ati gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli bá kúrò ní ìlú Gibetoni, wọ́n lọ dó ti ìlú Tirisa. Nígbà tí Simiri rí i pé ọwọ́ ti tẹ ìlú náà, ó lọ sí ibi ààbò tí ó wà ninu ààfin, ó tiná bọ ààfin, ó sì kú sinu iná; nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, tí ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, tí ó tọ ọ̀nà tí Jeroboamu tọ̀, ati fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá: tí ó mú kí àwọn ọmọ Israẹli náà dẹ́ṣẹ̀. Gbogbo nǹkan yòókù tí Simiri ṣe: gbogbo ìwà ọ̀tẹ̀ rẹ̀, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. Lẹ́yìn ikú Simiri àwọn ọmọ Israẹli pín sí ọ̀nà meji. Àwọn kan wà lẹ́yìn Tibini, ọmọ Ginati, pé òun ni kí ó jọba. Àwọn yòókù sì wà lẹ́yìn Omiri. Níkẹyìn, àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn Omiri ṣẹgun àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn Tibini, ọmọ Ginati. Tibini kú, Omiri sì jọba. Ní ọdún kọkanlelọgbọn tí Asa, ọba Juda ti wà lórí oyè, ni Omiri gorí oyè ní Israẹli. Ó sì jọba fún ọdún mejila. Ìlú Tirisa ni ó gbé fún ọdún mẹfa àkọ́kọ́. Lẹ́yìn náà, ó ra òkè Samaria ní ìwọ̀n talẹnti fadaka meji, lọ́wọ́ ọkunrin kan tí ń jẹ́ Ṣemeri. Omiri mọ odi yí òkè náà ká, ó sì sọ orúkọ ìlú tí ó kọ́ náà ní Samaria, gẹ́gẹ́ bí orúkọ Ṣemeri, ẹni tí ó ni òkè náà tẹ́lẹ̀. Nǹkan tí Omiri ṣe burú lójú OLUWA, ibi tí ó ṣe pọ̀ ju ti gbogbo àwọn tí wọ́n wà ṣáájú rẹ̀ lọ. Gbogbo ọ̀nà burúkú tí Jeroboamu ọmọ Nebati rìn ni òun náà ń tọ̀. Òun náà jẹ́ kí Israẹli dẹ́ṣẹ̀, ó sì mú OLUWA Ọlọrun Israẹli bínú nítorí oriṣa tí wọn ń bọ. Àwọn nǹkan yòókù tí Omiri ṣe ati iṣẹ́ akikanju tí ó ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. Omiri kú, wọ́n sì sin ín sí Samaria; Ahabu ọmọ rẹ̀ sì gorí oyè dípò rẹ̀. Ní ọdún kejidinlogoji tí Asa, ọba Juda gorí oyè ni Ahabu, ọmọ Omiri gorí oyè ní Israẹli, Ahabu sì jọba lórí Israẹli ní Samaria fún ọdún mejilelogun. Ahabu ọmọ Omiri ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA ju gbogbo àwọn tí wọ́n ṣáájú rẹ̀ lọ. Bí ẹni pé, gbogbo àìdára tí Ahabu ọba ṣe bíi ti Jeroboamu, ọmọ Nebati, kò burú tó, ó tún lọ fẹ́ Jesebẹli ọmọbinrin Etibaali, ọba Sidoni, ó sì ń bọ oriṣa Baali. Ó tẹ́ pẹpẹ kan fún oriṣa Baali ninu ilé tí ó kọ́ fún oriṣa náà, ní Samaria. Bákan náà, ó tún ṣe oriṣa Aṣera kan. Ahabu ṣe ohun tí ó bí OLUWA Ọlọrun Israẹli ninu ju gbogbo àwọn ọba Israẹli tí wọ́n jẹ ṣáájú rẹ̀ lọ. Ní àkókò ìgbà tirẹ̀ ni Hieli ará Bẹtẹli tún ìlú Jẹriko kọ́. Abiramu àkọ́bí rẹ̀ ọkunrin kú, nígbà tí Hieli fi ìpìlẹ̀ ìlú Jẹriko lélẹ̀. Segubu, àbíkẹ́yìn rẹ̀ ọkunrin sì tún kú bákan náà, nígbà tí ó gbé ìlẹ̀kùn sí ẹnubodè rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀, láti ẹnu Joṣua, ọmọ Nuni. Wolii kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Elija, ará Tiṣibe, ní Gileadi, sọ fún Ahabu pé, “Bí OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí mò ń sìn ti wà láàyè, mò ń sọ fún ọ pé, òjò kò ní rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìrì kò ní sẹ̀ fún ọdún mélòó kan, àfi ìgbà tí mo bá sọ pé, kí òjò rọ̀, tabi kí ìrì sẹ̀.” Lẹ́yìn náà, OLUWA sọ fún Elija pé, “Kúrò níhìn-ín, kí o doríkọ apá ìhà ìlà oòrùn, kí o sì fi ara pamọ́ lẹ́bàá odò Keriti, tí ó wà ní apá ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani. Ninu odò yìí ni o óo ti máa bu omi mu, mo sì ti pàṣẹ fún àwọn ẹyẹ ìwò kan pé kí wọ́n máa gbé oúnjẹ wá fún ọ níbẹ̀.” Elija bá lọ, ó ṣe bí OLUWA ti wí, ó sì ń gbé ẹ̀bá odò Keriti, ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani. Àwọn ẹyẹ ìwò ń gbé oúnjẹ ati ẹran wá fún un ní ojoojumọ, ní àràárọ̀ ati ní ìrọ̀lẹ́ ìrọ̀lẹ́, ó sì ń mu omi odò náà. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, odò náà gbẹ nítorí àìrọ̀ òjò ní ilẹ̀ náà. OLUWA bá tún sọ fún Elija pé, “Dìde nisinsinyii, kí o lọ sí ìlú Sarefati, ní agbègbè Sidoni, kí o sì máa gbé ibẹ̀. Mo ti pàṣẹ fún opó kan níbẹ̀ láti máa fún ọ ní oúnjẹ.” Elija bá lọ sí Sarefati. Bí ó ti dé ẹnu ọ̀nà ibodè ìlú náà, ó rí obinrin opó kan tí ń wá igi ìdáná. Ó wí fún obinrin yìí pé, “Jọ̀wọ́ lọ bá mi bu omi wá kí n mu.” Bí ó ti ń lọ bu omi náà, Elija tún pè é pada, ó ní, “Jọ̀wọ́ bá mi mú oúnjẹ díẹ̀ lọ́wọ́ sí i.” Obinrin náà dáhùn pé, “OLUWA Ọlọrun rẹ ń gbọ́, n kò ní oúnjẹ rárá. Gbogbo ohun tí mo ní kò ju ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun kan lọ, tí ó wà ninu àwokòtò kan; ati ìwọ̀nba òróró olifi díẹ̀, ninu kólòbó kan. Igi ìdáná díẹ̀ ni mò ń wá níhìn-ín, kí n fi se ìwọ̀nba oúnjẹ díẹ̀ tí ó kù, fún èmi ati ọmọ mi; pé kí a jẹ ẹ́, kí a sì máa dúró de ọjọ́ ikú.” Elija wí fún un pé, “Má bẹ̀rù. Lọ se oúnjẹ tí o fẹ́ sè, ṣugbọn kọ́kọ́ tọ́jú díẹ̀ lára rẹ̀, kí o sì gbé e wá fún mi. Lẹ́yìn náà, kí o lọ sè fún ara rẹ ati fún ọmọ rẹ. Nítorí ohun tí OLUWA Ọlọrun Israẹli wí ni pé, ìyẹ̀fun kò ní tán ninu ìkòkò rẹ, bẹ́ẹ̀ ni kólòbó òróró rẹ kò ní gbẹ títí tí OLUWA yóo fi rọ òjò sórí ilẹ̀.” Obinrin yìí bá lọ, ó ṣe bí Elija ti wí. Òun ati Elija ati gbogbo ará ilé rẹ̀ sì ń jẹ àjẹyó fún ọpọlọpọ ọjọ́. Ìyẹ̀fun kò tán ninu ìkòkò rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kólòbó òróró rẹ̀ kò sì gbẹ, bí OLUWA ti ṣèlérí fún un láti ẹnu Elija. Lẹ́yìn èyí, ọmọ obinrin opó yìí ṣàìsàn. Àìsàn náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ọmọ náà ṣàìsí. Obinrin náà bá bi Elija pé, “Eniyan Ọlọrun, kí ló dé tí o fi ṣe mí báyìí? Ṣé o wá sọ́dọ̀ mi láti rán Ọlọrun létí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi, ati láti ṣe ikú pa ọmọ mi ni.” Elija dáhùn pé, “Gbé ọmọ náà fún mi.” Ó bá gba òkú ọmọ náà lọ́wọ́ rẹ̀, ó gbé e gun orí òkè ilé lọ sinu yàrá tí ó ń gbé, ó sì tẹ́ ẹ sórí ibùsùn rẹ̀. Ó képe OLUWA, ó ní, “OLUWA, Ọlọrun mi, kí ló dé tí o fi jẹ́ kí irú ìdààmú yìí bá obinrin opó tí mò ń gbé ọ̀dọ̀ rẹ̀ yìí, tí o jẹ́ kí ọmọ rẹ̀ kú?” Elija bá na ara rẹ̀ sórí ọmọ yìí nígbà mẹta, ó sì ké pe OLÚWA, ó ní, “OLUWA Ọlọrun mi, jẹ́ kí ẹ̀mí ọmọ yìí tún pada sinu rẹ̀.” OLUWA dáhùn adura Elija, ẹ̀mí ọmọ náà sì tún pada sinu rẹ̀, ó sì sọjí. Elija gbé ọmọ náà sọ̀kalẹ̀ pada sọ́dọ̀ ìyá rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Wò ó! Ọmọ rẹ ti sọjí.” Obinrin náà sọ fún Elija pé, “Mo mọ̀ nisinsinyii pé eniyan Ọlọrun ni ọ́, ati pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ OLUWA tí ń ti ẹnu rẹ jáde.” Lẹ́yìn ọjọ́ pípẹ́, ní ọdún kẹta tí ọ̀dá ti dá, OLUWA sọ fún Elija pé, “Lọ fi ara rẹ han Ahabu ọba, n óo sì rọ̀jò sórí ilẹ̀.” Elija bá lọ fi ara han Ahabu. Ìyàn tí ó mú ní ìlú Samaria pọ̀ pupọ. Ahabu pe Ọbadaya, tí ó jẹ́ alabojuto ààfin. Ọbadaya jẹ́ ẹni tí ó bẹ̀rù OLUWA gan-an. Nígbà tí Jesebẹli bẹ̀rẹ̀ sí pa àwọn wolii OLUWA, Ọbadaya yìí ló kó ọgọrun-un ninu wọn pamọ́ sinu ihò àpáta meji, ó kó aadọta sinu ihò kọ̀ọ̀kan, ó sì ń fún wọn ní oúnjẹ ati omi. Ahabu sọ fún Ọbadaya pé, “Lọ wo gbogbo orísun omi ati àfonífojì ní gbogbo ilẹ̀ yìí, kí o wò ó bóyá a lè rí koríko láti fi bọ́ àwọn ẹṣin ati àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, kí wọ́n má baà kú.” Wọ́n ṣe àdéhùn ibi tí olukuluku yóo lọ wò ní gbogbo ilẹ̀ náà, olukuluku sì gba ọ̀nà tirẹ̀ lọ. Ahabu ọba lọ sí apá kan, Ọbadaya sì lọ sí apá keji. Bí Ọbadaya ti ń lọ, lójijì ni ó pàdé Elija. Ó ranti rẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó sì bi í léèrè pé, “Àbí ìwọ kọ́ ni, Elija, oluwa mi?” Elija dá a lóhùn pé, “Èmi ni, lọ sọ fún oluwa rẹ, ọba, pé èmi Elija wà níhìn-ín.” Ọbadaya bá bèèrè pé, “Kí ni mo ṣe, tí o fi fẹ́ fa èmi iranṣẹ rẹ, lé Ahabu ọba lọ́wọ́ láti pa? OLUWA Ọlọrun rẹ gbọ́, pé ọba ti wá ọ káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè ayé. Bí ọba ìlú kan, tabi tí orílẹ̀-èdè kan, bá sọ pé o kò sí ní ilẹ̀ òun, Ahabu á ní dandan, àfi kí wọ́n búra pé lóòótọ́ ni wọn kò rí ọ. Nisinsinyii, o wá sọ fún mi pé kí n lọ sọ fún oluwa mi pé o wà níhìn-ín. Bí mo bá kúrò lọ́dọ̀ rẹ tán tí ẹ̀mí Ọlọrun bá gbé ọ lọ sí ibi tí n kò mọ̀ ńkọ́? Bí mo bá lọ sọ fún Ahabu pé o wà níhìn-ín, tí kò bá rí ọ mọ́, pípa ni yóo pa mí; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé láti ìgbà èwe mi ni mo ti bẹ̀rù OLUWA. Àbí o kò gbọ́ nígbà tí Jesebẹli ń pa àwọn wolii OLUWA, pé mo kó ọgọrun-un ninu wọn pamọ́ sinu ihò àpáta meji, mo kó araadọta sinu ihò kọ̀ọ̀kan, mo sì ń fún wọn ní oúnjẹ ati omi. O ṣe wá sọ pé kí n lọ sọ fún oluwa mi pé o wà níhìn-ín? Pípa ni yóo pa mí.” Elija dá a lóhùn pé, “Ní orúkọ OLUWA àwọn ọmọ ogun, tí mò ń sìn, mo ṣèlérí fún ọ pé, n óo fara han ọba lónìí.” Ọbadaya bá lọ sọ fún ọba, ọba sì lọ pàdé Elija. Nígbà tí Ahabu rí Elija, ó wí fún un pé, “Ojú rẹ nìyí ìwọ tí ò ń yọ Israẹli lẹ́nu!” Elija dáhùn pé, “Èmi kọ́ ni mò ń yọ Israẹli lẹ́nu, ìwọ gan-an ni. Ìwọ ati ilé baba rẹ; nítorí ẹ ti kọ òfin OLUWA sílẹ̀, ẹ sì ń sin oriṣa Baali. Nítorí náà, pàṣẹ pé kí wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, kí wọ́n pàdé mi ní orí òkè Kamẹli. Kí aadọtalenirinwo (450) àwọn wolii oriṣa Baali ati àwọn irinwo (400) wolii oriṣa Aṣera, tí ayaba Jesebẹli ń bọ náà bá wọn wá.” Ahabu bá ranṣẹ pé gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ati àwọn wolii oriṣa Baali, pé kí wọ́n pàdé òun ní orí òkè Kamẹli. Elija bá súnmọ́ gbogbo àwọn eniyan, ó wí fún wọn pé, “Yóo ti pẹ́ tó, tí ẹ óo fi máa ṣe iyèméjì? Bí ó bá jẹ́ pé OLUWA ni Ọlọrun, ẹ máa sìn ín. Bí ó bá sì jẹ́ pé oriṣa Baali ni ẹ máa bọ ọ́.” Ṣugbọn àwọn eniyan náà kò sọ ohunkohun. Elija tún sọ fún wọn pé, “Èmi nìkan ṣoṣo ni wolii OLUWA tí ó ṣẹ́kù, ṣugbọn àwọn wolii oriṣa Baali tí wọ́n wà jẹ́ aadọtalenirinwo (450). Ẹ fún wa ní akọ mààlúù meji, kí àwọn wolii Baali mú ọ̀kan, kí wọ́n pa á, kí wọ́n sì gé e kéékèèké. Kí wọ́n kó o sórí igi, ṣugbọn kí wọ́n má fi iná sí i. Èmi náà yóo pa akọ mààlúù keji, n óo kó o sórí igi, n kò sì ní fi iná sí i. Lẹ́yìn náà, ẹ̀yin ẹ ké pe oriṣa Baali, Ọlọrun yín, èmi náà yóo sì ké pe OLUWA. Èyíkéyìí ninu wọn tí ó bá dáhùn, tí ó bá mú kí iná ṣẹ́, òun ni Ọlọrun.” Àwọn eniyan náà bá pariwo pé, “A gbà bẹ́ẹ̀.” Elija bá sọ fún àwọn wolii Baali pé, “Ẹ̀yin ni ẹ pọ̀, ẹ̀yin ẹ kọ́kọ́ mú akọ mààlúù kan, kí ẹ tọ́jú rẹ̀. Ẹ gbadura sí oriṣa yín ṣugbọn ẹ má fi iná sí igi ẹbọ yín.” Wọ́n mú akọ mààlúù tí wọ́n fún wọn, wọ́n pa á, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ké pe oriṣa Baali láti àárọ̀ títí di ọ̀sán. Wọ́n ń wí pé, “Baali, dá wa lóhùn!” Ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò fọhùn. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jó yípo pẹpẹ tí wọ́n kọ́. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò dá wọn lóhùn. Nígbà tí ó di ọ̀sán, Elija bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ pé, “Ẹ kígbe sókè, nítorí pé Ọlọrun ṣá ni. Bóyá ó ronú lọ ni, bóyá ó sì wọ ilé ìgbọ̀nsẹ̀ lọ ni; tabi ó lè jẹ́ pé ó lọ sí ìrìn àjò ni. Bóyá ó sùn ni, ẹ sì níláti jí i.” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí kígbe sókè, wọ́n ń fi idà ati ọ̀kọ̀ ya ara wọn lára, gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn, títí tí ẹ̀jẹ̀ fi bò wọ́n. Nígbà tí ọ̀sán pọ́n, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kígbe, wọ́n ń sáré kiri bíi wèrè, títí tí ó fi di àkókò ìrúbọ ọ̀sán, ṣugbọn Baali kò dá wọn lóhùn rárá. Kò tilẹ̀ fọhùn. Nígbà tó yá, Elija wí fún gbogbo àwọn eniyan náà pé, “Ẹ súnmọ́ mi níhìn-ín.” Gbogbo wọn súnmọ́ ọn, wọ́n sì yí i ká. Ó bá tún pẹpẹ OLUWA tí ó ti wó ṣe. Ó kó òkúta mejila jọ, òkúta kọ̀ọ̀kan dúró fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Jakọbu, ẹni tí OLUWA sọ fún pé, “Israẹli ni orúkọ rẹ yóo máa jẹ́.” Ó fi òkúta mejeejila náà kọ́ pẹpẹ ní orúkọ OLUWA. Ó gbẹ́ kòtò kan yí pẹpẹ náà ká, kòtò náà tóbi tó láti gba òṣùnwọ̀n irúgbìn meji (nǹkan bíi lita mẹrinla). Lẹ́yìn náà, ó to igi sórí pẹpẹ, ó gé akọ mààlúù náà sí wẹ́wẹ́, ó sì tò wọ́n sórí igi. Ó ní kí wọ́n pọn ẹ̀kún ìkòkò omi ńlá mẹrin, kí wọ́n dà á sórí ẹbọ ati igi náà, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ní kí wọ́n tún da mẹrin mìíràn, wọ́n tún ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ní kí wọ́n tún ṣe bẹ́ẹ̀ lẹẹkẹta, wọ́n sì tún ṣe bẹ́ẹ̀. Omi náà ṣàn sílẹ̀ yí pẹpẹ ká, ó sì kún kòtò tí wọ́n gbẹ́ yípo. Nígbà tí ó di àkókò ìrúbọ ìrọ̀lẹ́, Elija súnmọ́ ibi pẹpẹ náà, ó sì gbadura pé, “OLUWA, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Israẹli, fi hàn lónìí pé ìwọ ni Ọlọrun Israẹli, ati pé iranṣẹ rẹ ni mí, ati pé gbogbo ohun tí mò ń ṣe yìí, pẹlu àṣẹ rẹ ni. Dá mi lóhùn, OLUWA, dá mi lóhùn; kí àwọn eniyan wọnyi lè mọ̀ pé ìwọ OLUWA ni Ọlọrun, ati pé ìwọ ni o fẹ́ yí ọkàn wọn pada sọ́dọ̀ ara rẹ.” OLUWA bá sọ iná sílẹ̀, iná náà sì jó ẹbọ náà ati igi, ati òkúta. Ó jó gbogbo ilẹ̀ ibẹ̀, ó sì lá gbogbo omi tí ó wà ninu kòtò. Nígbà tí àwọn eniyan náà rí i, wọ́n dojúbolẹ̀, wọ́n wí pé, “OLUWA ni Ọlọrun! OLUWA ni Ọlọrun!” Elija bá pàṣẹ pé, “Ẹ mú gbogbo àwọn wolii oriṣa Baali! Ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ninu wọn sá lọ.” Àwọn eniyan náà bá ki gbogbo wọn mọ́lẹ̀, Elija kó wọn lọ sí ibi odò Kiṣoni, ó sì pa wọ́n sibẹ. Lẹ́yìn náà, Elija sọ fún Ahabu ọba pé, “Lọ, jẹun, kí o wá nǹkan mu, nítorí mo gbọ́ kíkù òjò.” Nígbà tí Ahabu lọ jẹun, Elija gun orí òkè Kamẹli lọ, ó wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó sì ki orí bọ ààrin orúnkún rẹ̀ mejeeji. Ó sọ fún iranṣẹ rẹ̀ pé kí ó lọ wo apá ìhà òkun. Iranṣẹ náà lọ, ó sì pada wá, ó ní, òun kò rí nǹkankan. Elija sọ fún un pé, “Tún lọ ní ìgbà meje.” Ní ìgbà keje tí ó pada dé, ó ní, “Mo rí ìkùukùu kan tí ń bọ̀ láti inú òkun, ṣugbọn kò ju àtẹ́lẹwọ́ lọ.” Elija pàṣẹ fún iranṣẹ rẹ̀ pé kí ó lọ sọ fún ọba, kí ó kó sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, kí ó sì sọ̀kalẹ̀ pada sí ilé kí òjò má baà ká a mọ́ ibi tí ó wà. Láìpẹ́, ìkùukùu bo gbogbo ojú ọ̀run, afẹ́fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́, òjò ńlá sì bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀. Ahabu kó sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó sì pada lọ sí Jesireeli. Agbára OLUWA sọ̀kalẹ̀ sórí Elija, ó di àmùrè rẹ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí sáré lọ; ó sì ṣáájú Ahabu dé ẹnubodè Jesireeli. Ahabu ọba sọ gbogbo ohun tí Elija ṣe fún Jesebẹli, aya rẹ̀, ati bí ó ti pa gbogbo wolii oriṣa Baali. Jesebẹli bá rán oníṣẹ́ kan sí Elija pẹlu ìbúra pé, “Kí àwọn oriṣa pa mí, bí n kò bá pa ọ́ ní ìwòyí ọ̀la, bí o ti pa àwọn wolii Baali.” Ẹ̀rù ba Elija, ó sì sá fún ikú. Ó lọ sí Beeriṣeba, ní ilẹ̀ Juda. Ó fi iranṣẹ rẹ̀ sibẹ, ṣugbọn òun alára wọ inú ijù lọ ní ìrìn odidi ọjọ́ kan kí ó tó dúró. Ó bá jókòó lábẹ́ ìbòòji igi kan, ó wo ara rẹ̀ bíi kí òun kú. Ó sì gbadura sí OLUWA pé, “OLUWA, ó tó gẹ́ẹ́ báyìí! Kúkú pa mí. Kí ni mo fi sàn ju àwọn baba mi lọ?” Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi náà, ó sì sùn. Lójijì, angẹli kan fi ọwọ́ kàn án, ó sì wí fún un pé, “Dìde kí o jẹun.” Ó wò yíká, ó sì rí ìṣù àkàrà kan, ati ìkòkò omi kan lẹ́bàá ìgbèrí rẹ̀. Ó jẹun, ó mu omi, ó sì tún dùbúlẹ̀. Angẹli OLUWA náà pada wa, ó jí i, ó sì wí fún un pé, “Dìde kí o jẹun, kí ìrìn àjò náà má baà pọ̀jù fún ọ.” Elija dìde, ó jẹun, ó sì tún mu omi. Oúnjẹ náà sì fún un ní agbára láti rìn fún ogoji ọjọ́ tọ̀sán-tòru títí tí ó fi dé orí òkè Horebu, òkè Ọlọrun. Ó dé ibi ihò àpáta kan, ó sì sùn níbẹ̀ mọ́jú ọjọ́ keji. OLUWA bá a sọ̀rọ̀, ó bi í pé, “Elija, kí ni ò ń ṣe níhìn-ín?” Elija dáhùn pé, “Mò ń jowú nítorí ìwọ OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli ti kọ majẹmu rẹ tì, wọ́n ti wó pẹpẹ rẹ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wolii rẹ. Èmi nìkan ṣoṣo ni mo ṣẹ́kù, wọ́n sì fẹ́ gba ẹ̀mí èmi náà.” OLUWA wí fún un pé, “Lọ dúró níwájú mi ní orí òkè yìí.” OLUWA ba kọjá lọ, ẹ̀fúùfù líle kán fẹ́, ó la òkè náà, ó sì fọ́ àwọn òkúta rẹ̀ sí wẹ́wẹ́ níwájú OLUWA. Ṣugbọn OLUWA kò sí ninu ẹ̀fúùfù líle náà. Lẹ́yìn ẹ̀fúùfù náà, ìṣẹ̀lẹ̀ kan ṣẹ̀, gbogbo ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mì tìtì. Ṣugbọn OLUWA kò sí ninu ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, iná ńlá kan bẹ̀rẹ̀ sí jó. Ṣugbọn OLUWA kò sí ninu iná náà. Lẹ́yìn iná náà, ohùn kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ kan rọra sọ̀rọ̀ jẹ́ẹ́jẹ́. Nígbà tí Elija gbọ́ ohùn náà, ó fi ẹ̀wù rẹ̀ bojú, ó jáde, ó sì dúró ní ẹnu ọ̀nà ihò àpáta náà. Ohùn kan bi í pé, “Elija, kí ni ò ń ṣe níhìn-ín?” Ó bá dáhùn pé, “Mò ń jowú nítorí OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli ti da majẹmu rẹ̀, wọ́n ti wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wolii rẹ̀. Èmi nìkan ṣoṣo, ni mo ṣẹ́kù, wọ́n sì fẹ́ gba ẹ̀mí èmi náà.” OLUWA dá a lóhùn pé, “Pada lọ sinu aṣálẹ̀ ẹ̀bá Damasku. Nígbà tí o bá dé ibẹ̀, fi àmì òróró yan Hasaeli ní ọba Siria. Yan Jehu, ọmọ Nimṣi, ní ọba Israẹli, kí o sì yan Eliṣa, ọmọ Ṣafati, ará Abeli Mehola, ní wolii dípò ara rẹ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá bọ́ lọ́wọ́ idà Hasaeli, Jehu ni yóo pa á, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì bọ́ lọ́wọ́ idà Jehu, Eliṣa ni yóo pa á. Sibẹsibẹ n óo dá ẹẹdẹgbaarin (7,000) eniyan sí, ní ilẹ̀ Israẹli: àwọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí mi, tí wọn kò tíì kúnlẹ̀ fún oriṣa Baali, tabi kí wọ́n fi ẹnu wọn kò ó lẹ́nu.” Nígbà tí ó yá, Elija bá kúrò níbẹ̀, bí ó ti ń lọ ó bá Eliṣa ọmọ Ṣafati níbi tí ó tí ń fi àjàgà mààlúù mejila kọ ilẹ̀. Àjàgà mààlúù mọkanla wà níwájú rẹ̀, bí wọ́n ti ń kọ ilẹ̀ lọ. Òun alára wà pẹlu àjàgà mààlúù tí ó kẹ́yìn, ó ń fi í kọ ilẹ̀. Elija kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó bọ́ ẹ̀wù rẹ̀, ó gbé e wọ Eliṣa. Eliṣa fi àjàgà mààlúù rẹ̀ sílẹ̀, ó sáré tẹ̀lé Elija, o wí fún un pé, “Jẹ́ kí n lọ dágbére fún baba ati ìyá mi, kí n fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu, kí n tó máa tẹ̀lé ọ.” Elija dá a lóhùn pé, “Pada lọ, àbí, kí ni mo ṣe fún ọ?” Eliṣa bá pada lẹ́yìn rẹ̀ sí ibi tí àwọn akọ mààlúù rẹ̀ wà, ó pa wọ́n. Ó fi igi tí ó fi ṣe àjàgà wọn ṣe igi ìdáná, ó bá se ẹran wọn. Ó pín ẹran náà fún àwọn eniyan, wọ́n sì jẹ ẹ́. Ó bá pada lọ sọ́dọ̀ Elija, ó ń tẹ̀lé e, ó sì ń ṣe iranṣẹ fún un. Benhadadi, ọba Siria kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ; àwọn ọba mejilelọgbọn ni wọ́n wá láti ràn án lọ́wọ́, pẹlu gbogbo ẹṣin, ati gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun wọn. Wọ́n dó ti ìlú Samaria, wọ́n sì bá a jagun. Ó rán àwọn oníṣẹ́ sí ààrin ìlú pé kí wọ́n sọ fún Ahabu, ọba Israẹli pé, “Benhadadi ọba ní, ‘Tèmi ni gbogbo fadaka ati wúrà rẹ, tèmi náà sì ni àwọn tí wọ́n dára jùlọ lára àwọn aya rẹ, ati àwọn ọmọ rẹ.’ ” Ahabu ọba bá ranṣẹ pada pé, “Gẹ́gẹ́ bí o ti sọ, oluwa mi, ìwọ ni o ni mí ati gbogbo ohun tí mo ní.” Àwọn oníṣẹ́ náà tún pada wá sí ọ̀dọ̀ Ahabu, wọ́n ní Benhadadi ọba tún ranṣẹ, ó ní, òun ti ranṣẹ sí Ahabu pé kí ó kó fadaka rẹ̀ ati wúrà rẹ̀, ati àwọn obinrin rẹ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀ fún òun, ṣugbọn òun óo rán àwọn oníṣẹ́ òun sí i ní ìwòyí ọ̀la láti yẹ ààfin rẹ̀ wò ati ilé àwọn oníṣẹ́ rẹ̀, kí wọ́n sì kó ohunkohun tí ó bá wù wọ́n. Nígbà náà ni Ahabu ọba ranṣẹ pe gbogbo àwọn àgbààgbà ilẹ̀ náà, ó wí fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí i pé ọkunrin yìí ń wá ìjàngbọ̀n? Ó ranṣẹ wá pé kí n kó fadaka ati wúrà mi, ati àwọn obinrin mi, ati àwọn ọmọ mi fún òun, n kò sì bá a jiyàn.” Àwọn àgbààgbà bá dá a lóhùn pé, “Má dá a lóhùn rárá, má sì gbà fún un.” Ahabu bá ranṣẹ pada sí Benhadadi ọba pé, “Mo faramọ́ ohun tí ó kọ́kọ́ bèèrè fún, ṣugbọn n kò lè gba ti ẹẹkeji yìí.” Àwọn oníṣẹ́ náà pada lọ jíṣẹ́ fún Benhadadi ọba. Benhadadi ọba tún ranṣẹ pada pé, “Àwọn oriṣa ń gbọ́! Mò ń kó àwọn eniyan bọ̀ láti pa ìlú Samaria run, wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi jẹ́ pé ọwọ́ lásán ni wọn yóo fi kó gbogbo erùpẹ̀ ìlú náà. Bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, kí àwọn oriṣa pa mí.” Ahabu ọba ranṣẹ pada, ó ní, “Jagunjagun kan kì í fọ́nnu kí ó tó lọ sójú ogun, ó di ìgbà tí ó bá lọ sógun tí ó bá bọ̀.” Nígbà tí Benhadadi gbọ́ iṣẹ́ yìí níbi tí ó ti ń mu ọtí pẹlu àwọn ọba yòókù ninu àgọ́, ó pàṣẹ fún àwọn eniyan rẹ̀ pé kí wọ́n lọ múra ogun. Wọ́n bá múra láti bá Samaria jagun. Wolii kan bá tọ Ahabu ọba lọ, ó wí fún un pé, “OLUWA ní kí n wí fún ọ pé, ‘Ṣé o rí gbogbo àwọn ọmọ ogun yìí bí wọ́n ti pọ̀ tó? Wò ó! N óo fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí wọn lónìí, o óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’ ” Ahabu bèèrè pé, “Ta ni yóo ṣáájú ogun?” Wolii náà dáhùn pé, “OLUWA ní, àwọn iranṣẹ gomina ìpínlẹ̀ ni.” Ahabu tún bèèrè pé, “Ta ni yóo bẹ̀rẹ̀ ogun náà?” Wolii náà dáhùn pé, “Ìwọ gan-an ni.” Ọba bá pe gbogbo àwọn iranṣẹ tí wọ́n wà lábẹ́ àwọn gomina ìpínlẹ̀ jọ, gbogbo wọn jẹ́ ojilerugba ó dín mẹjọ (232), ó sì pe gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli jọ, gbogbo wọ́n jẹ́ ẹẹdẹgbaarin (7,000). Nígbà tí ó di ọ̀sán, wọ́n kó ogun jáde, bí Benhadadi ọba ati àwọn ọba mejilelọgbọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ti ń mu ọtí àmupara ninu àgọ́ wọn. Àwọn ọ̀dọ́ ọmọ ogun ni wọ́n ṣáájú ogun Israẹli, wọ́n bá lọ ṣígun bá Benhadadi. Àwọn amí tí ọba Benhadadi rán jáde lọ ròyìn fún un pé, àwọn eniyan kan ń jáde bọ̀ láti ìlú Samaria. Ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n mú wọn láàyè, wọ́n ìbáà máa bọ̀ wá jagun, wọn ìbáà sì máa bọ̀ wá sọ̀rọ̀ alaafia. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ogun ṣe jáde ní ìlú: àwọn ọ̀dọ́ ọmọ ogun ni wọ́n ṣáájú ogun, lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ ogun Israẹli tẹ̀lé wọn. Olukuluku wọn pa ẹni tí ó dojú ìjà kọ. Àwọn ọmọ ogun Siria bá sá. Àwọn ọmọ ogun Israẹli sì ń lé wọn lọ. Ṣugbọn Benhadadi, ọba Siria, ti gun ẹṣin sá lọ, pẹlu àwọn jagunjagun tí wọ́n gun ẹṣin. Ahabu ọba bá lọ sójú ogun, ó kó ọpọlọpọ ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun; ó ṣẹgun àwọn ọmọ ogun Siria, ó sì pa ọpọlọpọ ninu wọn. Wolii náà tún tọ Ahabu ọba lọ, ó wí fún un pé, “Pada lọ kó àwọn ọmọ ogun rẹ jọ, kí o sì ṣètò dáradára; nítorí pé, ọba Siria yóo tún bá ọ jagun ní ìbẹ̀rẹ̀ àkókò òjò.” Àwọn oníṣẹ́ Benhadadi ọba wí fún un pé, “Oriṣa orí òkè ni oriṣa àwọn ọmọ Israẹli. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ṣẹgun wa. Ṣugbọn bí a bá gbógun tì wọ́n ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, a óo ṣẹgun wọn. Nítorí náà, mú àwọn ọba mejeejilelọgbọn kúrò ní ààyè wọn gẹ́gẹ́ bí olórí ogun, kí o sì fi àwọn ọ̀gágun gidi dípò wọn. Kí o wá kó àwọn ọmọ ogun mìíràn jọ, kí wọ́n pọ̀ bí i ti àkọ́kọ́, kí ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun pọ̀ bákan náà. A óo bá àwọn ọmọ Israẹli jagun ní pẹ̀tẹ́lẹ̀; láìsí àní àní, a óo sì ṣẹgun wọn.” Ọba Benhadadi gba ìmọ̀ràn wọn, ó sì ṣe ohun tí wọ́n wí. Ní ọdún tí ó tẹ̀lé e, ní ìbẹ̀rẹ̀ àkókò òjò, ó kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ, ó sì kó wọn lọ sí ìlú Afeki, láti gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n kó àwọn ọmọ ogun Israẹli náà jọ, wọ́n sì wá àwọn ohun ìjà ogun fún wọn. Àwọn náà jáde sójú ogun, wọ́n pàgọ́ tiwọn siwaju àwọn ọmọ ogun Siria, wọ́n wá dàbí agbo ewúrẹ́ meji kéékèèké níwájú àwọn ọmọ ogun Siria tí wọ́n tò lọ rẹrẹẹrẹ ninu pápá. Wolii kan tọ Ahabu lọ, ó sì wí fún un pé, “OLUWA ní kí n wí fún ọ pé, ‘Nítorí pé àwọn ará Siria sọ pé, “ọlọrun orí òkè ni OLUWA, kì í ṣe Ọlọrun àfonífojì,” nítorí náà ni n óo ṣe fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí ọ̀pọ̀ eniyan wọnyi, o óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’ ” Àgọ́ àwọn ọmọ ogun Israẹli ati ti àwọn ọmọ ogun Siria kọjú sí ara wọn, wọn kò sì kúrò ní ààyè wọn fún ọjọ́ meje. Nígbà tí ó di ọjọ́ keje wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jagun. Àwọn ọmọ ogun Israẹli pa ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) ọmọ ogun tí wọn ń fi ẹsẹ̀ rìn lára àwọn ti Siria ní ọjọ́ kan. Àwọn ọmọ ogun Siria yòókù sì sá lọ sí ìlú Afeki; odi ìlú náà sì wó pa ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaarin (27,000) tí ó kù ninu wọn. Benhadadi pàápàá sá wọ inú ìlú lọ, ó sì sá pamọ́ sinu yàrá ní ilé kan. Àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ wí fún un pé, “A gbọ́ pé àwọn ọba Israẹli a máa ní ojú àánú, jẹ́ kí á sán aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́dìí, kí á wé okùn mọ́ ara wa lórí, kí á sì lọ sọ́dọ̀ ọba Israẹli, bóyá yóo dá ẹ̀mí rẹ sí.” Nítorí náà, wọ́n sán aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́dìí, wọ́n sì wé okùn mọ́ ara wọn lórí. Wọ́n bá tọ Ahabu ọba lọ, wọ́n ní, “Benhadadi, iranṣẹ rẹ, ní kí á jíṣẹ́ fún ọ pé kí o jọ̀wọ́ kí o dá ẹ̀mí òun sí.” Ahabu bá dáhùn pé, “Ó ṣì wà láàyè? Arakunrin mi ni!” Àwọn iranṣẹ Benhadadi ti ń ṣọ́ Ahabu fún àmì rere kan tẹ́lẹ̀. Nígbà tí Ahabu ti fẹnu kan “Arakunrin”, kíá ni wọ́n ti gba ọ̀rọ̀ yìí mọ́ ọn lẹ́nu, wọ́n ní, “Bẹ́ẹ̀ ni, arakunrin rẹ ni Benhadadi.” Ahabu wí fún wọn pé, “Ẹ lọ mú un wá.” Nígbà tí Benhadadi dé, Ahabu ní kí ó wọ inú kẹ̀kẹ́ ogun pẹlu òun. Benhadadi bá wí fún un pé, “N óo dá àwọn ìlú tí baba mi gbà lọ́wọ́ baba rẹ pada fún ọ, o óo sì lè kọ́ àwọn ilé ìtajà fún ara rẹ ní ìlú Damasku gẹ́gẹ́ bí baba mi ti ṣe ní ìlú Samaria.” Ahabu dá a lóhùn pé, “Bí o bá ṣe ohun tí o wí yìí, n óo dá ọ sílẹ̀.” Ahabu bá bá a dá majẹmu, ó sì fi sílẹ̀ kí ó máa lọ. OLUWA pàṣẹ fún ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wolii kan, pé kí ó sọ fún wolii ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan pé kí ó jọ̀wọ́ kí ó lu òun, ṣugbọn wolii náà kọ̀, kò lù ú. Ni ó bá wí fún un pé, “Nítorí pé o ṣàìgbọràn sí àṣẹ OLUWA, bí o bá ti ń kúrò lọ́dọ̀ mi gẹ́lẹ́ ni kinniun yóo pa ọ́.” Bí ó sì ti kúrò lóòótọ́, kinniun kan yọ sí i, ó sì pa á. Wolii yìí rí ọkunrin mìíràn, o sì bẹ̀ ẹ́ pé, “Lù mí.” Ọkunrin yìí lù ú, lílù náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi pa á lára. Wolii yìí bá mú aṣọ kan, ó fi wé ojú rẹ̀. Ó yíra pada, kí ẹnikẹ́ni má baà mọ̀ ọ́n, ó sì lọ dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà de ìgbà tí ọba Israẹli yóo kọjá. Bí ọba ti ń kọjá lọ, wolii yìí kígbe pé, “Kabiyesi, nígbà tí mò ń jà lójú ogun, ọmọ ogun ẹlẹgbẹ́ mi kan mú ọ̀tá kan tí ó mú ní ìgbèkùn wá sọ́dọ̀ mi, ó ní kí n máa ṣọ́ ọkunrin yìí, ó ní bí ó bá sá lọ, èmi ni n óo kú dípò rẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀ sì kọ́, mo níláti san ìwọ̀n talẹnti fadaka kan gẹ́gẹ́ bí owó ìtanràn. Ṣugbọn níbi tí mo ti ń lọ sókè sódò, tí mò ń ṣe àwọn nǹkan mìíràn, ọkunrin yìí sá lọ.” Ọba dá a lóhùn pé, “Ìwọ náà ti dá ara rẹ lẹ́jọ́, bẹ́ẹ̀ gan-an ni yóo sì rí.” Wolii náà sáré tu aṣọ tí ó fi wé ojú, lẹsẹkẹsẹ ọba sì mọ̀ pé ọ̀kan ninu àwọn wolii ni. Wolii náà bá wí fún ọba pé, “OLUWA ní, nítorí pé o jẹ́ kí ẹni tí mo ti pinnu láti pa sá lọ, ẹ̀mí rẹ ni n óo fi dípò ẹ̀mí rẹ̀, n óo sì pa àwọn eniyan rẹ dípò àwọn eniyan rẹ̀.” Ọba bá pada lọ sí ààfin rẹ̀ ní Samaria, pẹlu ìpayà ati ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn. Ọkunrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Naboti, ará Jesireeli, ní ọgbà àjàrà kan. Ní Jesireeli ni ọgbà yìí wà, lẹ́bàá ààfin Ahabu, ọba Samaria. Ní ọjọ́ kan, Ahabu pe Naboti ó ní, “Fún mi ni ọgbà àjàrà rẹ, mo fẹ́ lo ilẹ̀ náà fún ọgbà ewébẹ̀ nítorí ó súnmọ́ tòsí ààfin mi. N óo fún ọ ní ọgbà àjàrà tí ó dára ju èyí lọ dípò rẹ̀, tabi tí ó bá sì wù ọ́, n óo san owó rẹ̀ fún ọ.” Naboti dáhùn pé, “Ọwọ́ àwọn baba ńlá mi ni mo ti jogún ọgbà àjàrà yìí; OLUWA má jẹ́ kí n rí ohun tí n óo fi gbé e fún ọ.” Ahabu bá pada lọ sílé pẹlu ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn ati ibinu, nítorí ohun tí Naboti ará Jesireeli wí fún un. Ó dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀, ó kọjú sí ògiri, kò sì jẹun. Jesebẹli, aya rẹ̀, wọlé tọ̀ ọ́ lọ, ó sì bi í pé, “Kí ló dé tí ọkàn rẹ fi rẹ̀wẹ̀sì tóbẹ́ẹ̀ tí o kò fi jẹun?” Ahabu dá a lóhùn pé, “Mo sọ fún Naboti pé mo fẹ́ ra ọgbà àjàrà rẹ̀, tabi bí ó bá fẹ́, kí ó jẹ́ kí n fún un ni òmíràn dípò rẹ̀; ṣugbọn ó ní òun kò lè fún mi ní ọgbà àjàrà òun.” Jesebẹli, aya rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Họ́wù! Ṣebí ìwọ ni ọba Israẹli, àbí ìwọ kọ́? Dìde nílẹ̀ kí o jẹun, kí o sì jẹ́ kí inú rẹ dùn, n óo gba ọgbà àjàrà Naboti fún ọ.” Jesebẹli bá kọ ìwé ní orúkọ Ahabu, ó fi òǹtẹ̀ Ahabu tẹ̀ ẹ́, ó fi ranṣẹ sí àwọn àgbààgbà ati àwọn eniyan ńláńlá ní ìlú tí Naboti ń gbé. Ohun tí ó kọ sinu ìwé náà ni pé, “Ẹ kéde ọjọ́ ààwẹ̀ kan, ẹ pe àwọn eniyan jọ, ẹ sì fi Naboti jókòó ní ipò ọlá. Kí ẹ wá àwọn eniyankeniyan meji kan tí wọ́n ya aṣa, kí wọ́n jókòó níwájú rẹ̀, kí wọ́n sì fi ẹ̀sùn kàn án pé, ó bú Ọlọrun ati ọba. Lẹ́yìn náà, ẹ mú un jáde sẹ́yìn odi ìlú, kí ẹ sì sọ ọ́ lókùúta pa.” Àwọn àgbààgbà ati àwọn eniyan ńláńlá tí wọn ń gbé ìlú náà ṣe bí Jesebẹli ti ní kí wọ́n ṣe ninu ìwé tí ó kọ ranṣẹ sí wọn. Wọ́n kéde ọjọ́ ààwẹ̀ kan, wọ́n pe àwọn eniyan jọ, wọ́n sì fún Naboti ní ipò ọlá láàrin wọn. Àwọn eniyankeniyan meji tí wọ́n ya aṣa yìí jókòó níwájú rẹ̀, wọ́n sì purọ́ mọ́ ọn lójú gbogbo eniyan pé ó bú Ọlọrun ati ọba. Wọ́n bá fà á jáde sẹ́yìn odi ìlú, wọ́n sì sọ ọ́ lókùúta pa. Lẹ́yìn náà wọ́n ranṣẹ sí Jesebẹli pé àwọn ti sọ Naboti lókùúta pa. Bí Jesebẹli ti gbọ́ pé wọ́n ti sọ Naboti lókùúta pa, ó sọ fún Ahabu pé, “Gbéra nisinsinyii, kí o sì lọ gba ọgbà àjàrà tí Naboti kọ̀ láti tà fún ọ, nítorí pé ó ti kú.” Lẹsẹkẹsẹ bí Ahabu ti gbọ́ pé Naboti ti kú, ó lọ sí ibi ọgbà àjàrà náà, ó sì gbà á. OLUWA bá sọ fún Elija wolii ará Tiṣibe pé, “Lọ bá Ahabu, ọba Israẹli, tí ń gbé Samaria; o óo bá a ninu ọgbà àjàrà Naboti, tí ó lọ gbà. Sọ pé, OLUWA ní kí o sọ fún un pé ṣé o ti pa ọkunrin yìí, o sì ti gba ọgbà àjàrà rẹ̀? Wí fún un pé, mo ní, ibi tí ajá ti lá ẹ̀jẹ̀ Naboti gan-an ni ajá yóo ti lá ẹ̀jẹ̀ tirẹ̀ náà.” Nígbà tí Ahabu rí Elija, ó bi í pé, “O tún ti rí mi kọ́, ìwọ ọ̀tá mi?” Elija bá dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo tún ti rí ọ; nítorí pé o ti fa ara rẹ kalẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ burúkú níwájú OLUWA. OLUWA ní òun óo jẹ́ kí ibi bá ọ, òun óo pa ọ́ rẹ́, òun ó sì run gbogbo ọkunrin tí ń bẹ ninu ìdílé rẹ, ati ẹrú ati ọmọ. Ó ní bí òun ti ṣe ìdílé Jeroboamu, ọmọ Nebati, ati ti Baaṣa, ọmọ Ahija, bẹ́ẹ̀ ni òun óo ṣe ìdílé rẹ; nítorí o ti jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli dẹ́ṣẹ̀, o sì ti mú òun OLUWA bínú. Ní ti Jesebẹli, OLUWA ní, ajá ni yóo jẹ òkú rẹ̀ láàrin ìlú Jesireeli. Ẹni tí ó bá kú sí ààrin ìlú ninu ìdílé ìwọ Ahabu, ajá ni yóo jẹ òkú rẹ̀, ẹni tí ó bá sì kú sinu pápá, àwọn ẹyẹ ni yóo jẹ òkú rẹ̀.” (Kò sí ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún iṣẹ́ burúkú lójú OLUWA gẹ́gẹ́ bíi Ahabu, tí Jesebẹli aya rẹ̀, ń tì gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n láti ṣe iṣẹ́ burúkú. Gbogbo ọ̀nà ìríra tí àwọn ará Amori ń gbà bọ oriṣa ni Ahabu pàápàá ń gbà bọ oriṣa rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni lílé sì ni OLUWA lé àwọn ará Amori jáde kúrò ní ilẹ̀ Kenaani fún àwọn ọmọ Israẹli nígbà tí wọn ń bọ̀.) Nígbà tí Elija parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ahabu fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn, ó bọ́ wọn kúrò, ó sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀. Ó gbààwẹ̀, orí aṣọ ọ̀fọ̀ ni ó sì ń sùn; ó sì ń káàkiri pẹlu ìdoríkodò ati ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn. OLUWA tún sọ fún Elija pé, “Ǹjẹ́ o ṣe akiyesi bí Ahabu ti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú mi? Nítorí pé ó ti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ báyìí, n kò ní jẹ́ kí ibi tí mo wí ṣẹlẹ̀ nígbà ayé rẹ̀. Ó di ìgbà ayé ọmọ rẹ̀ kí n tó jẹ́ kí ibi ṣẹlẹ̀ sí ìdílé rẹ̀.” Fún ọdún mẹta lẹ́yìn èyí, kò sí ogun rárá láàrin ilẹ̀ Israẹli ati ilẹ̀ Siria. Nígbà tí ó di ọdún kẹta, Jehoṣafati, ọba Juda, lọ bẹ Ahabu, ọba Israẹli wò. Ahabu bi àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé àwa ni a ni ìlú Ramoti Gileadi? A kò sì ṣe ohunkohun láti gbà á pada lọ́wọ́ ọba Siria.” Ó bi Jehoṣafati pé, “Ṣé o óo bá mi lọ, kí á jọ lọ gbógun ti ìlú Ramoti Gileadi?” Jehoṣafati bá dá a lóhùn pé, “Bí ó bá ti yá ọ, ó yá mi. Tìrẹ ni àwọn eniyan mi, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ẹṣin mi pẹlu.” Jehoṣafati fi ṣugbọn kan kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí a kọ́kọ́ wádìí lọ́wọ́ OLUWA ná.” Ahabu ọba Israẹli bá pe àwọn wolii bí irinwo (400) jọ, ó bi wọ́n pé ṣé kí òun lọ gbógun ti ìlú Ramoti Gileadi àbí kí òun má lọ? Wọ́n dá a lóhùn pé, “Máa lọ, nítorí OLUWA yóo jẹ́ kí ọwọ́ rẹ tẹ̀ ẹ́, yóo fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí rẹ̀.” Ṣugbọn Jehoṣafati bèèrè pé, “Ṣé kò tún sí wolii OLUWA mìíràn mọ́, tí a lè wádìí lọ́dọ̀ rẹ̀?” Ahabu dá a lóhùn pé, “Ẹnìkan tí ó kù, tí ó tún lè bá wa wádìí lọ́dọ̀ OLUWA ni Mikaaya ọmọ Imila, ṣugbọn mo kórìíra rẹ̀; nítorí pé kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere nípa mi rí, àfi burúkú.” Jehoṣafati dá a lóhùn pé, “Kabiyesi, má wí bẹ́ẹ̀.” Ahabu bá pàṣẹ fún ọ̀kan ninu àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ ní ààfin pé kí ó lọ pe Mikaaya, ọmọ Imila, wá kíákíá. Ọba Israẹli ati Jehoṣafati ọba Juda wọ aṣọ ìgúnwà wọn, wọ́n sì jókòó lórí ìtẹ́ wọn, ní ibi ìpakà tí ó wà lẹ́nu bodè Samaria; gbogbo àwọn wolii sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀ níwájú wọn. Ọ̀kan ninu wọn tí ń jẹ́ Sedekaya, ọmọ Kenaana fi irin ṣe ìwo, ó sì wí fún Ahabu pé, “OLUWA ní kí n wí fún ọ pé, ohun tí ìwọ óo fi bá àwọn ará Siria jà nìyí títí tí o óo fi ṣẹgun wọn patapata.” Nǹkan kan náà ni gbogbo àwọn wolii yòókù ń wí, gbogbo wọn ní kí Ahabu lọ gbógun ti Ramoti Gileadi, wọ́n ní OLUWA yóo fún un ní ìṣẹ́gun. Iranṣẹ tí ọba rán lọ pe Mikaaya wí fún un pé, “Gbogbo àwọn wolii yòókù ni wọ́n ti fi ohùn ṣọ̀kan tí wọ́n sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere fún ọba, ìwọ náà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ ó bá tiwọn mu, kí o sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere.” Ṣugbọn Mikaaya dáhùn pé, “OLUWA alààyè, ń gbọ́! Ohun tí OLUWA bá wí fún mi ni n óo sọ.” Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ ọba, ọba bi í pé, “Mikaaya, ṣé kí á lọ gbógun ti Ramoti Gileadi ni, àbí kí á má lọ?” Mikaaya dáhùn pé, “Lọ gbógun tì í, OLUWA yóo fún ọ ní ìṣẹ́gun.” Ṣugbọn Ahabu tún bi í pé, “Ìgbà mélòó ni n óo sọ fún ọ pé, nígbà tí o bá sọ̀rọ̀ fún mi ní orúkọ OLUWA, kí o máa sọ òtítọ́ fún mi?” Mikaaya bá dáhùn pé, “Mo rí àwọn ọmọ ogun Israẹli tí wọ́n fọ́n káàkiri gbogbo orí òkè, bí aguntan tí kò ní olùṣọ́. OLUWA sì wí pé, ‘Àwọn eniyan wọnyi kò ní olórí, kí olukuluku wọn pada lọ sí ilé ní alaafia.’ ” Ahabu bá wí fún Jehoṣafati pé, “Ṣebí mo ti sọ fún ọ pé kì í sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere nípa mi, àfi burúkú?” Mikaaya dáhùn pé, “Ó dára, fetí sílẹ̀, kí o gbọ́ ohun tí OLUWA wí, mo rí i tí OLUWA jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run, gbogbo ogun ọ̀run sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ọ̀tún ati tòsì, OLUWA bèèrè pé, ‘Ta ni yóo lọ tan Ahabu jẹ, kí ó lè lọ sí Ramoti Gileadi kí wọ́n sì pa á níbẹ̀?’ Bí angẹli kan ti ń sọ ọ̀kan bẹ́ẹ̀ ni òmíràn sì ń sọ nǹkan mìíràn. Ẹ̀mí kan bá jáde siwaju OLUWA, ó ní, ‘N óo lọ tàn án jẹ.’ OLUWA bá bi í pé, ‘Ọgbọ́n wo ni o óo dá?’ Ẹ̀mí náà dáhùn pé, ‘N óo mú kí gbogbo àwọn wolii Ahabu purọ́ fún un.’ OLUWA bá dáhùn pé, ‘Lọ tàn án jẹ, o óo ṣe àṣeyọrí.’ “Nítorí náà, gbọ́ nisinsinyii, OLUWA ni ó jẹ́ kí àwọn wolii wọnyi máa purọ́ fún ọ, nítorí pé ó ti pinnu láti jẹ́ kí ibi bá ọ.” Sedekaya wolii, ọmọ Kenaana bá súnmọ́ Mikaaya, ó gbá a létí, ó ní, “Ọ̀nà wo ni Ẹ̀mí OLUWA gbà fi mí sílẹ̀, tí ó sì ń bá ìwọ sọ̀rọ̀.” Mikaaya bá dá a lóhùn pé, “O óo rí i nígbà tí ó bá di ọjọ́ náà, tí o bá sá wọ yàrá inú patapata lọ, láti fi ara pamọ́.” Ọba Israẹli bá dáhùn pé, “Ẹ mú Mikaaya pada lọ fún Amoni, gomina ìlú yìí, ati Joaṣi ọmọ ọba. Ẹ ní, èmi ọba ni mo ní kí ẹ sọ fún wọn pé, kí wọ́n jù ú sinu ẹ̀wọ̀n, kí wọn sì máa fún un ní àkàrà lásán ati omi, títí tí n óo fi pada dé ní alaafia.” Mikaaya bá dáhùn pé, “Bí o bá pada dé ní alaafia, a jẹ́ pé kì í ṣe OLUWA ló gba ẹnu mi sọ̀rọ̀.” Ó ní, “Gbogbo eniyan, ṣé ẹ gbọ́ ohun tí mo wí?” Ahabu, ọba Israẹli, ati Jehoṣafati, ọba Juda, bá lọ gbógun ti ìlú Ramoti Gileadi. Ahabu wí fún Jehoṣafati pé, “Bí a ti ń lọ sí ojú ogun yìí, n óo paradà, kí ẹnikẹ́ni má baà dá mi mọ̀. Ṣugbọn ìwọ, wọ aṣọ oyè rẹ.” Ahabu, ọba Israẹli, bá paradà, ó sì lọ sójú ogun. Ọba Siria ti pàṣẹ fún àwọn olórí kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ mejeejilelọgbọn, pé kí wọ́n má lépa ẹnikẹ́ni lójú ogun, àfi ọba Israẹli nìkan. Nítorí náà, nígbà tí wọ́n rí Jehoṣafati ọba, wọ́n ní, “Dájúdájú ọba Israẹli nìyí.” Wọ́n bá yipada láti bá a jà; ṣugbọn Jehoṣafati kígbe. Nígbà tí wọ́n mọ̀ pé kì í ṣe òun ni ọba Israẹli, wọ́n bá pada lẹ́yìn rẹ̀. Ṣugbọn ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun Siria déédé ta ọfà rẹ̀, ọfà náà sì bá Ahabu ọba níbi tí àwọn irin ìgbàyà rẹ̀ ti fi ẹnu ko ara wọn. Ó bá wí fún ẹni tí ń wa kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ pé kí ó gbé òun kúrò lójú ogun, nítorí pé òun ti fara gbọgbẹ́. Ogun gbóná gidigidi ní ọjọ́ náà. Ọwọ́ ni wọ́n fi ti ọba Ahabu ninu kẹ̀kẹ́ ogun tí ó wà, tí ó sì kọjú sí àwọn ará Siria. Nígbà tí yóo sì fi di ìrọ̀lẹ́, ó ti kú. Ẹ̀jẹ̀ tí ń ṣàn láti ojú ọgbẹ́ rẹ̀ sì ti dà sí ìsàlẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun náà. Nígbà tí oòrùn ń lọ wọ̀, wọ́n kéde fún gbogbo àwọn ọmọ ogun pé, “Kí olukuluku pada sí agbègbè rẹ̀! Kí kaluku kọrí sí ìlú rẹ̀!” Bẹ́ẹ̀ ni Ahabu ọba ṣe kú; wọ́n gbé òkú rẹ̀ lọ sí Samaria, wọ́n sì sin ín sibẹ. Wọ́n lọ fọ kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ní adágún Samaria, àwọn ajá lá ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, àwọn aṣẹ́wó sì lọ wẹ̀ ninu adágún náà gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀ pé yóo rí. Gbogbo àwọn nǹkan yòókù tí Ahabu ọba ṣe, ati àkọsílẹ̀ bí ó ṣe fi eyín erin ṣe iṣẹ́ ọnà sí ààfin rẹ̀, ati ti gbogbo ìlú tí ó tẹ̀dó, wà ninu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. Lẹ́yìn tí òun kú ni Ahasaya ọmọ rẹ̀ gun orí oyè. Ní ọdún kẹrin tí Ahabu, ọba Israẹli, gun orí oyè, ni Jehoṣafati, ọmọ Asa, gun orí oyè ní ilẹ̀ Juda. Ọmọ ọdún marundinlogoji ni Jehoṣafati nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹẹdọgbọn. Asuba ọmọ Ṣilihi ni ìyá rẹ̀. Ohun tí ó dára lójú OLUWA, tí Asa baba rẹ̀ ṣe ni òun náà ṣe; ṣugbọn kò wó àwọn pẹpẹ ìrúbọ tí wọ́n wà káàkiri. Àwọn eniyan tún ń rúbọ, wọ́n sì tún ń sun turari níbẹ̀. Jehoṣafati bá ọba Israẹli ṣọ̀rẹ́, alaafia sì wà láàrin wọn. Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoṣafati ṣe, gbogbo iṣẹ́ akikanju rẹ̀, ati gbogbo ogun tí ó jà, wà ninu àkọsílẹ̀ Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. Gbogbo àwọn aṣẹ́wó ọkunrin tí ó kù ní ilé àwọn oriṣa láti àkókò Asa, baba rẹ̀, ni ó parun ní ilẹ̀ náà. Kò sí ọba ní ilẹ̀ Edomu. Adelé ọba kan ní ń ṣàkóso ilẹ̀ náà. Jehoṣafati ọba kan àwọn ọkọ̀ ojú omi bíi ti ìlú Taṣiṣi, láti kó wọn lọ sí ilẹ̀ Ofiri láti lọ wá wúrà. Ṣugbọn wọn kò lè lọ nítorí pé àwọn ọkọ̀ náà bàjẹ́ ní Esiongeberi. Ahasaya ọba Israẹli, ọmọ Ahabu, ọba Israẹli sọ fún Jehoṣafati pé kí àwọn eniyan òun bá àwọn eniyan rẹ̀ tu ọkọ̀ lọ, ṣugbọn Jehoṣafati kò gbà. Nígbà tí ó yá, Jehoṣafati kú, wọ́n sì sin ín sí ibojì àwọn ọba, ní ìlú Dafidi, baba ńlá rẹ̀. Jehoramu ọmọ rẹ̀ sì gorí oyè dípò rẹ̀. Ní ọdún kẹtadinlogun tí Jehoṣafati, ọba Juda, gun orí oyè ni Ahasaya, ọmọ Ahabu, gun orí oyè ní ilẹ̀ Israẹli, ó sì jọba ní Samaria fún ọdún meji. Ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé àpẹẹrẹ burúkú Ahabu, baba rẹ̀, ati ti Jesebẹli, ìyá rẹ̀, ati ti Jeroboamu, ọmọ Nebati, àwọn tí wọ́n jẹ́ kí Israẹli dẹ́ṣẹ̀. Ó bọ oriṣa Baali, ó sì mú OLUWA Ọlọrun Israẹli bínú ní gbogbo ọ̀nà bí baba rẹ̀ ti ṣe. Lẹ́yìn ikú Ahabu ọba, àwọn ará Moabu ṣọ̀tẹ̀ sí Israẹli, wọ́n fẹ́ fi tipátipá gba òmìnira. Ahasaya ọba ṣubú láti orí òkè ilé rẹ̀ ní Samaria, ó sì farapa pupọ. Nítorí náà ni ó ṣe rán oníṣẹ́ lọ bèèrè lọ́wọ́ Baalisebubu, oriṣa Ekironi, bóyá òun yóo sàn ninu àìsàn náà tabi òun kò ní sàn. Ṣugbọn angẹli OLUWA kan pàṣẹ fún wolii Elija, ará Tiṣibe pé, “Lọ pàdé àwọn oníṣẹ́ ọba Samaria, kí o sì bèèrè lọ́wọ́ wọn pé, ‘Ṣé nítorí pé kò sí Ọlọrun ní Israẹli ni ẹ fi ń lọ wádìí nǹkan lọ́dọ̀ Baalisebubu, oriṣa Ekironi?’ Ẹ lọ sọ fún ọba pé, báyìí ni OLUWA wí, ‘O kò ní sàn ninu àìsàn náà, kíkú ni o óo kú.’ ” Elija sì ṣe gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un. Àwọn oníṣẹ́ náà pada sọ́dọ̀ ọba, ọba bá bèèrè pé, “Kí ló dé tí ẹ fi pada?” Wọ́n dáhùn pé, “Ọkunrin kan pàdé wa lọ́nà, ó sì sọ fún wa pé, ‘Ẹ pada sọ́dọ̀ ọba tí ó ran yín, kí ẹ sì sọ fún un pé, “OLUWA ní, ṣé nítorí pé kò sí Ọlọrun ní Israẹli ni o fi rán oníṣẹ́ lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Baalisebubu, oriṣa Ekironi? Nítorí náà o kò ní sàn ninu àìsàn yìí, o óo kú ni.” ’ ” Ọba bá bèèrè pé, “Irú ọkunrin wo ni ó wá pàdé yín lójú ọ̀nà, tí ó sọ bẹ́ẹ̀ fun yín?” Wọ́n dáhùn pé, “Ọkunrin náà wọ aṣọ tí wọ́n fi awọ ẹranko ṣe, ó sì di àmùrè awọ mọ́ ẹ̀gbẹ́.” Ọba dáhùn pé, “Elija ará Tiṣibe ni.” Ọba bá rán ọ̀gágun kan ati àwọn aadọta ọmọ ogun rẹ̀ kí wọ́n lọ mú Elija. Ọ̀gágun náà rí Elija níbi tí ó jókòó sí ní téńté òkè, ó sì wí fún un pé, “Ìwọ eniyan Ọlọrun, ọba sọ pé kí o sọ̀kalẹ̀ wá.” Elija sì dáhùn pé, “Bí mo bá jẹ́ eniyan Ọlọrun, kí iná wá láti ọ̀run, kí ó sì jó ìwọ ati àwọn aadọta ọmọ ogun rẹ!” Lẹ́sẹ̀kan náà, iná wá láti ọ̀run, ó sì jó ọ̀gágun náà ati gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀. Ọba bá tún rán ọ̀gágun mìíràn ati àwọn aadọta ọmọ-ogun rẹ̀ láti lọ mú Elija. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Elija òun náà tún sọ fún un pé, “Ìwọ eniyan Ọlọrun, ọba sọ pé kí o sọ̀kalẹ̀ wá kíákíá.” Elija tún dáhùn pé, “Bí mo bá jẹ́ eniyan Ọlọrun, kí iná wá láti ọ̀run, kí ó sì jó ìwọ ati àwọn aadọta ọmọ ogun rẹ!” Lẹ́sẹ̀ kan náà, iná wá láti ọ̀run, ó sì jó ọ̀gágun náà ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ọba rán ọ̀gágun mìíràn ati àwọn aadọta ọmọ ogun rẹ̀. Ṣugbọn ó gòkè lọ sọ́dọ̀ Elija, ó sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bẹ̀ ẹ́ pé, “Ìwọ eniyan Ọlọrun jọ̀wọ́ mo bẹ̀ ọ́, ṣàánú fún mi ati fún àwọn iranṣẹ rẹ wọnyi, kí o sì dá ẹ̀mí wa sí. Iná tí ó wá láti ọ̀run ni ó pa àwọn ọ̀gágun meji ti iṣaaju ati àwọn ọmọ ogun wọn, nítorí náà mo bẹ̀ ọ́, dá ẹ̀mí mi sí.” Nígbà náà ni angẹli OLUWA sọ fún Elija pé kí ó bá wọn lọ, kí ó má sì bẹ̀rù. Elija bá bá a lọ sọ́dọ̀ ọba. Elija sọ fún ọba pé, báyìí ni OLUWA wí, “Nítorí pé o rán oníṣẹ́ láti lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ Baalisebubu, oriṣa Ekironi, bí ẹni pé kò sí Ọlọrun ní Israẹli láti wádìí lọ́wọ́ rẹ̀, nítorí náà, o kò ní sàn ninu àìsàn yìí, kíkú ni o óo kú.” Ahasaya sì kú gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA tí Elija sọ. Ṣugbọn nítorí pé kò ní ọmọkunrin kankan Joramu, arakunrin rẹ̀ jọba lẹ́yìn rẹ̀, ní ọdún keji tí Jehoramu ọmọ Jehoṣafati jọba ní Juda. Gbogbo nǹkan yòókù tí Ahasaya ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. Nígbà tí àkókò tó fún OLUWA láti fi ààjà gbé Elija lọ sí ọ̀run, Elija ati Eliṣa kúrò ní Giligali. Elija sọ fún Eliṣa pé, “Dúró níhìn-ín nítorí pé OLUWA rán mi sí Bẹtẹli.” Ṣugbọn Eliṣa dáhùn pé, “Bí OLUWA ti wà láàyè tí ìwọ náà sì wà láàyè, n kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà wọ́n jọ lọ sí Bẹtẹli. Àwọn ọmọ wolii tí wọn ń gbé Bẹtẹli tọ Eliṣa wá, wọ́n bi í pé, “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé OLUWA yóo mú ọ̀gá rẹ lọ lónìí?” Eliṣa dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀, ṣugbọn ẹ má ṣe sọ ohunkohun nípa rẹ̀.” Elija tún sọ fún Eliṣa pé, “Dúró níhìn-ín, nítorí pé OLUWA rán mi sí Jẹriko.” Eliṣa dáhùn pé, “Bí OLUWA ti wà láàyè, tí ìwọ náà sì wà láàyè, n kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà wọ́n jọ lọ sí Jẹriko. Àwọn ọmọ wolii tí wọn ń gbé Jẹriko tọ Eliṣa wá, wọ́n sì bi í pé, “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé OLUWA yóo mú ọ̀gá rẹ lọ lónìí?” Eliṣa dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀, ṣugbọn ẹ má ṣe sọ ohunkohun nípa rẹ̀.” Elija tún sọ fún Eliṣa pé, “Dúró níhìn-ín nítorí pé OLUWA rán mi sí odò Jọdani.” Eliṣa dáhùn pé, “Bí OLUWA ti ń bẹ, tí ìwọ náà sì wà láàyè, n kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà wọ́n jọ ń lọ. Aadọta ninu àwọn ọmọ àwọn wolii náà sì dúró ní òkèèrè, wọ́n ń wò wọ́n. Elija ati Eliṣa sì dúró létí odò Jọdani. Elija bọ́ aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀, ó fi lu odò náà, odò sì pín sí meji títí tí Elija ati Eliṣa fi kọjá sí òdìkejì odò lórí ìyàngbẹ ilẹ̀. Níbẹ̀ ni Elija ti bèèrè lọ́wọ́ Eliṣa pé, “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe fún ọ kí á tó gbé mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ.” Eliṣa sì dáhùn pé, “Mo bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ìlọ́po meji agbára rẹ bà lé mi.” Elija dáhùn pé, “Ohun tí o bèèrè yìí ṣòro, ṣugbọn bí o bá rí mi nígbà tí wọ́n bá ń gbé mi lọ, o óo rí ohun tí o bèèrè gbà. Ṣugbọn bí o kò bá rí mi, o kò ní rí i gbà.” Bí wọ́n ti ń lọ tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀, lójijì kẹ̀kẹ́-ogun iná ati ẹṣin iná gba ààrin wọn kọjá, Elija sì bá ààjà gòkè lọ sí ọ̀run. Bí Eliṣa ti rí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ó kígbe pe Elija, ó ní, “Baba mi, baba mi, kẹ̀kẹ́-ogun Israẹli ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.” Kò rí Elija mọ́, ó bá fa aṣọ rẹ̀ ya sí meji láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn. Lẹ́yìn náà ó mú aṣọ àwọ̀lékè Elija tí ó bọ́ sílẹ̀, ó sì pada lọ dúró ní etí odò Jọdani. Ó fi aṣọ àwọ̀lékè tí ó já bọ́ sílẹ̀ lára Elija lu odò, ó sì kígbe pé, “Níbo ni OLUWA Ọlọrun Elija wà?” Lẹ́yìn náà odò pín sí meji, Eliṣa bá kọjá sí òdìkejì. Nígbà tí àwọn ọmọ àwọn wolii tí wọ́n wà ní Jẹriko rí i, wọ́n ní, “Ẹ̀mí Elija ti wà lára Eliṣa!” Wọ́n lọ pàdé rẹ̀, wọ́n wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n ní, “Aadọta ọkunrin alágbára wà pẹlu àwa iranṣẹ rẹ, jọ́wọ́ jẹ́ kí wọ́n lọ wá ọ̀gá rẹ, bóyá Ẹ̀mí OLUWA tí ó gbé e lọ ti jù ú sílẹ̀ ní orí ọ̀kan ninu àwọn òkè agbègbè yìí, tabi ninu àfonífojì kan.” Eliṣa sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má ṣe rán wọn lọ.” Ṣugbọn wọ́n rọ̀ ọ́ títí tí ojú fi ń tì í, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ rán wọn lọ.” Wọ́n bá rán àwọn aadọta ọkunrin lọ, wọ́n wá Elija ní àwọn orí òkè ati àwọn àfonífojì fún ọjọ́ mẹta, ṣugbọn wọn kò rí i. Wọ́n pada wá jábọ̀ fún Eliṣa ní Jẹriko, ó sì wí fún wọn pé, “Ṣebí mo ti sọ fun yín pé kí ẹ má lọ?” Àwọn ọkunrin ìlú náà wá sọ́dọ̀ Eliṣa, wọ́n sọ fún un pé, “Ìlú yìí dára gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ti mọ̀, ṣugbọn omi tí à ń mu kò dára, bẹ́ẹ̀ ni ilẹ̀ náà sì jẹ́ aṣálẹ̀.” Eliṣa bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ bu iyọ̀ sinu abọ́ tuntun, kí ẹ sì gbé e wá fún mi.” Wọ́n bá ṣe bí ó ti wí. Lẹ́yìn náà, ó jáde lọ sí ibi orísun omi náà, ó da iyọ̀ náà sí i, ó sì wí pé, “Báyìí ni OLUWA wí, ‘Mo sọ omi yìí di ọ̀tun lónìí, kò ní fa ikú mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ba oyún jẹ́ mọ́.’ ” Láti ìgbà náà ni omi náà ti dára títí di òní olónìí gẹ́gẹ́ bí Eliṣa ti sọ. Eliṣa kúrò níbẹ̀, ó lọ sí Bẹtẹli. Bí ó ti ń lọ, àwọn ọmọdekunrin kan ní ìlú náà bẹ̀rẹ̀ sí fi Eliṣa ṣe ẹlẹ́yà; wọ́n ń wí pé, “Kúrò níbí, ìwọ apárí! Kúrò níbí, ìwọ apárí!” Nígbà tí ó yí ojú pada, tí ó rí wọn, ó ṣépè lé wọn ní orúkọ OLUWA, abo ẹranko beari meji sì jáde láti inú igbó, wọ́n fa mejilelogoji ninu àwọn ọmọ náà ya. Eliṣa sì lọ sí òkè Kamẹli, láti ibẹ̀, ó lọ sí Samaria. Ní ọdún kejidinlogun tí Jehoṣafati jọba ní Juda, Joramu, ọmọ Ahabu, jọba lórí Israẹli ní Samaria. Ó sì wà lórí oyè fún ọdún mejila. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ó dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA, ṣugbọn ó wó òpó oriṣa Baali tí Baba rẹ̀ mọ, ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kò sì pọ̀ tó ti baba rẹ̀ tabi ti Jesebẹli ìyá rẹ̀. Ó mú kí Israẹli dẹ́ṣẹ̀ lọpọlọpọ gẹ́gẹ́ bíi Jeroboamu, tí ó ti jọba ṣáájú kò sì ronupiwada. Meṣa, ọba Moabu, a máa sin aguntan; ní ọdọọdún, a máa fún ọba Israẹli ní ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) ọ̀dọ́ aguntan ati irun ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) àgbò, gẹ́gẹ́ bí ìṣákọ́lẹ̀. Ṣugbọn lẹ́yìn tí Ahabu kú, ọba Moabu ṣọ̀tẹ̀, kò san ìṣákọ́lẹ̀ náà fún ọba Israẹli mọ́. Joramu ọba bá gbéra ní Samaria, ó sì kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ. Ó ranṣẹ sí Jehoṣafati ọba Juda pé, “Ọba Moabu ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi, ṣé o óo bá mi lọ láti bá a jagun?” Jehoṣafati dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, n óo lọ, ìwọ ni o ni mí, ìwọ ni o sì ni àwọn ọmọ ogun mi ati àwọn ẹṣin mi pẹlu.” Jehoṣafati bèèrè pé, “Ọ̀nà wo ni a óo gbà lọ?” Joramu sì dáhùn pé, “Ọ̀nà aṣálẹ̀ Edomu ni.” Ni Joramu, ati ọba Juda ati ọba Edomu bá gbéra láti lọ sójú ogun. Lẹ́yìn tí wọ́n ti rìn fún ọjọ́ meje, kò sí omi mímu mọ́ fún wọn ati fún àwọn ẹranko tí wọ́n ru ẹrù wọn. Joramu ọba ní, “Ó mà ṣe o, OLUWA pe àwa ọba mẹtẹẹta jọ láti fi wá lé ọba Moabu lọ́wọ́.” Ó bá bèèrè pé, “Ṣé kò sí wolii OLUWA kan níhìn-ín tí ó lè bá wa wádìí lọ́wọ́ OLUWA?” Ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ Joramu bá dáhùn pé, “Eliṣa ọmọ Ṣafati, tí ó jẹ́ iranṣẹ Elija, wà níhìn-ín.” Jehoṣafati dáhùn pé, “Wolii òtítọ́ ni.” Àwọn ọba mẹtẹẹta náà bá lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Eliṣa sọ fún Joramu ọba pé, “Lọ sọ́dọ̀ àwọn wolii baba ati ìyá rẹ. Àbí, kí ló pa èmi ati ìwọ pọ̀?” Joramu dáhùn pé, “Rárá, OLUWA ni ó ti pe àwa ọba mẹtẹẹta yìí jọ láti fi wá lé ọba Moabu lọ́wọ́.” Eliṣa bá dáhùn pé, “Bí OLUWA àwọn ọmọ ogun, ẹni tí mò ń sìn ṣe wà láàyè, n kì bá tí dá ọ lóhùn bí kò bá sí ti Jehoṣafati, ọba Juda, tí ó bá ọ wá.” Ó ní, “Ẹ pe akọrin kan wá.” Bí akọrin náà ti ń kọrin ni agbára OLUWA bà lé Eliṣa, ó bá ní, “OLUWA ní òun óo sọ àwọn odò gbígbẹ wọnyi di adágún omi. Ẹ kò ní rí ìjì tabi òjò, sibẹsibẹ àwọn odò gbígbẹ náà yóo kún fún omi, ti yóo fi jẹ́ pé ẹ̀yin ati àwọn mààlúù yín ati àwọn ẹran ọ̀sìn yín yóo rí ọpọlọpọ omi mu. Nǹkan kékeré ni èyí jẹ́ níwájú OLUWA, yóo fun yín ní agbára láti borí àwọn ará Moabu. Ẹ óo ṣẹgun àwọn ìlú olódi ati àwọn ìlú dáradára wọn, ẹ óo gé gbogbo igi dáradára, ẹ ó dí gbogbo orísun omi wọn; ẹ óo sì da òkúta sí gbogbo ilẹ̀ oko wọn.” Ní ọjọ́ keji, ní àkókò ìrúbọ òwúrọ̀, omi ya wá láti apá Edomu, títí tí gbogbo ilẹ̀ fi kún fún omi. Nígbà tí àwọn ará Moabu gbọ́ pé àwọn ọba mẹtẹẹta ń bọ̀ láti gbógun tì wọ́n, wọ́n pe gbogbo àwọn tí wọ́n lè lọ sógun jọ, ati àgbà ati ọmọde, wọ́n sì fi wọ́n sí àwọn ààlà ilẹ̀ wọn. Nígbà tí wọ́n jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, tí oòrùn ń ràn sórí omi náà, àwọn ará Moabu rí i pé omi tí ó wà níwájú àwọn pọ́n bí ẹ̀jẹ̀. Wọ́n kígbe pé, “Ẹ wo ẹ̀jẹ̀! Dájúdájú àwọn ọba mẹtẹẹta wọnyi ti bá ara wọn jà, wọ́n sì ti pa ara wọn, ẹ jẹ́ kí á lọ kó ìkógun ninu ibùdó-ogun wọn.” Ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé ibùdó-ogun náà, àwọn ọmọ ogun Israẹli kọlù wọ́n, títí tí wọ́n fi sá pada; wọ́n sì ń pa wọ́n ní ìpakúpa bí wọ́n ti ń lé wọn lọ. Wọ́n pa àwọn ìlú wọn run, gbogbo ilẹ̀ oko tí ó dára ni wọ́n da òkúta sí títí tí gbogbo wọn fi kún. Wọ́n dí gbogbo orísun omi, wọ́n sì gé gbogbo àwọn igi dáradára. Kiri Heresi tíí ṣe olú-ìlú wọn nìkan ni wọn kò pa run, ṣugbọn àwọn tí wọn ń ta kànnàkànnà yí i ká, wọ́n sì ṣẹgun rẹ̀. Nígbà tí ọba Moabu rí i pé ogun náà le pupọ, ó mú ẹẹdẹgbẹrin (700) ọkunrin tí wọ́n ń lo idà, ó gbìyànjú láti la ààrin ogun kọjá níwájú ọba Edomu, ṣugbọn kò ṣeéṣe. Nítorí náà, ó fi àkọ́bí rẹ̀ ọkunrin, tí ó yẹ kí ó jọba lẹ́yìn rẹ̀ rú ẹbọ sísun sí oriṣa Moabu, ní orí odi ìlú náà. Ibinu ńlá dé bá àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì fi í sílẹ̀, wọ́n pada lọ sí ilẹ̀ wọn. Iyawo ọ̀kan ninu àwọn ọmọ àwọn wolii tọ Eliṣa lọ, ó sì sọ fún un pé, “Olúwa mi, iranṣẹ rẹ, ọkọ mi, ti kú, gẹ́gẹ́ bí o ti mọ̀, ó jẹ́ ẹni tí ó bẹ̀rù OLUWA nígbà ayé rẹ̀. Ẹnìkan tí ó jẹ lówó kí ó tó kú fẹ́ kó àwọn ọmọkunrin mi mejeeji lẹ́rú, nítorí gbèsè baba wọn.” Eliṣa bèèrè pé, “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe fún ọ? Sọ ohun tí o ní nílé fún mi.” Obinrin náà dáhùn pé, “N kò ní ohunkohun, àfi ìkòkò òróró kan.” Eliṣa sọ fún un pé, “Lọ yá ọpọlọpọ ìkòkò lọ́wọ́ àwọn aládùúgbò rẹ. Lẹ́yìn náà, kí ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ wọlé, nígbà tí ẹ bá sì ti ti ìlẹ̀kùn yín tán, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí da òróró náà sinu àwọn ìkòkò náà, kí ẹ sì máa gbé wọn sí ẹ̀gbẹ́ kan bí wọ́n bá ti ń kún.” Obinrin náà lọ sinu ilé rẹ̀ pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n sì ti ìlẹ̀kùn wọn; ó bá bẹ̀rẹ̀ sí da òróró náà sinu àwọn ìkòkò náà bí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe ń gbé wọn wá. Nígbà tí gbogbo àwọn ìkòkò náà kún, obinrin náà bèèrè bóyá ìkòkò kù, àwọn ọmọ rẹ̀ sì dáhùn pé ó ti tán, òróró náà sì dá. Ó bá pada lọ sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún wolii Eliṣa. Eliṣa wí fún un pé, “Lọ ta àwọn òróró náà kí o sì san gbèsè rẹ ninu rẹ̀, kí ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ máa ná ìyókù.” Ní ọjọ́ kan Eliṣa lọ sí Ṣunemu, níbi tí obinrin ọlọ́rọ̀ kan ń gbé; obinrin náà sì pe Eliṣa wọlé kí ó wá jẹun. Láti ìgbà náà, ilé obinrin yìí ni Eliṣa ti máa ń jẹun ní Ṣunemu. Obinrin náà sọ fún ọkọ rẹ̀ pé, “Mo wòye pé ọkunrin tí ó ń wá síbí yìí jẹ́ ẹni mímọ́ Ọlọ́run. Jẹ́ kí á ṣe yàrá kékeré kan sí òkè ilé wa, kí á gbé ibùsùn, tabili, àga ati fìtílà sibẹ, kí ó lè máa dé sibẹ nígbàkúùgbà tí ó bá wá síbí.” Ní ọjọ́ kan tí Eliṣa pada lọ sí Ṣunemu, ó wọ inú yàrá náà lọ láti sinmi. Ó bá rán Gehasi iranṣẹ rẹ̀ kí ó pe obinrin náà wá. Nígbà tí ó wọlé ó dúró níwájú Eliṣa. Eliṣa sọ fún Gehasi kí ó bèèrè lọ́wọ́ obinrin náà ohun tí ó fẹ́ kí òun ṣe fún un, fún gbogbo nǹkan tí ó ti ṣe fún àwọn. Ó ní, bóyá ó fẹ́ kí òun sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún ọba ni tabi fún balogun? Obinrin náà dáhùn pé ààrin àwọn eniyan òun ni òun ń gbé. Eliṣa bá bèèrè lọ́wọ́ Gehasi pé, “Kí ni mo lè ṣe fún un nígbà náà?” Gehasi ní, “Kò bímọ, ọkọ rẹ̀ sì ti di arúgbó.” Eliṣa bá rán Gehasi kí ó pe obinrin náà wá. Nígbà tí ó dé, ó dúró ní ẹnu ọ̀nà. Eliṣa sọ fún un pé, “Níwòyí àmọ́dún, o óo fi ọwọ́ rẹ gbé ọmọkunrin.” Obinrin náà dáhùn pé, “Háà! Oluwa mi, eniyan Ọlọrun ni ọ́, nítorí náà má ṣe parọ́ fún iranṣẹbinrin rẹ.” Ṣugbọn obinrin náà lóyún ó sì bí ọmọkunrin ní akoko náà ní ọdún tí ó tẹ̀lé e gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Eliṣa. Ní ọjọ́ kan, lẹ́yìn tí ọmọ náà dàgbà, ó lọ bá baba rẹ̀ ninu oko níbi tí wọ́n ti ń kórè. Lójijì, ó kígbe pe baba rẹ̀, ó ní, “Orí mi! Orí mi!” Baba rẹ̀ sì sọ fún iranṣẹ kan kí ó gbé ọmọ náà lọ sọ́dọ̀ ìyá rẹ̀. Nígbà tí iranṣẹ náà gbé ọmọ náà dé ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ gbé e lé ẹsẹ̀ títí ọmọ náà fi kú ní ọ̀sán ọjọ́ náà. Obinrin náà bá gbé òkú ọmọ náà lọ sí yàrá Eliṣa, ó tẹ́ ẹ sí orí ibùsùn rẹ̀, ó ti ìlẹ̀kùn, ó sì jáde. Ó kígbe pe ọkọ rẹ̀ pé, “Jọ̀wọ́ rán iranṣẹ kan sí mi pẹlu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan. Mo fẹ́ sáré lọ rí eniyan Ọlọ́run, n óo pada dé kíákíá.” Ọkọ rẹ̀ bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ló dé tí o fi fẹ́ lọ rí i lónìí? Òní kì í ṣe ọjọ́ oṣù tuntun tabi ọjọ́ ìsinmi.” Ó sì dáhùn pé, “Kò séwu.” Lẹ́yìn tí wọ́n ti di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ní gàárì tán, ó sọ fún iranṣẹ náà pé, “Jẹ́ kí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà máa sáré dáradára, kí ó má sì dẹ̀rìn, àfi bí mo bá sọ pé kí ó má sáré mọ́.” Ó lọ bá Eliṣa ní orí òkè Kamẹli. Eliṣa rí i tí ó ń bọ̀ lókèèrè, ó bá sọ fún Gehasi, iranṣẹ rẹ̀, pé, “Wò ó! Obinrin ará Ṣunemu nì ni ó ń bọ̀ yìí! Sáré lọ pàdé rẹ̀ kí o sì bèèrè alaafia rẹ̀ ati ti ọkọ rẹ̀ ati ti ọmọ rẹ̀ pẹlu.” Obinrin náà dá Gehasi lóhùn pé, “Alaafia ni gbogbo wa wà.” Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Eliṣa, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì di ẹsẹ̀ rẹ̀ mú. Gehasi súnmọ́ ọn láti tì í kúrò, ṣugbọn Eliṣa wí fún un pé, “Fi obinrin náà sílẹ̀, ṣé o kò rí i pé inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi ni? OLUWA kò sì bá mi sọ nǹkankan nípa rẹ̀.” Obinrin náà bá sọ fún Eliṣa pé, “Ǹjẹ́ mo tọrọ ọmọ lọ́wọ́ rẹ bí? Ǹjẹ́ n kò sọ fún ọ kí o má ṣe tàn mí jẹ?” Eliṣa bá sọ fún Gehasi pé, “Ṣe gírí, kí o mú ọ̀pá mi lọ́wọ́, kí o sì máa lọ. Bí o bá pàdé ẹnikẹ́ni lọ́nà, má ṣe kí i, bí ẹnikẹ́ni bá kí ọ, má dáhùn.” Nígbà náà ni ìyá ọmọ náà wí pé “Bí OLUWA tí ń bẹ láàyè tí ẹ̀mí ìwọ pàápàá sì ń bẹ, n kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Gehasi bá dìde, ó bá a lọ. Ó lọ fi ọ̀pá Eliṣa lé ọmọ náà lójú, ṣugbọn ọmọ náà kò jí. Ó bá pada lọ sọ fún Eliṣa pé ọmọ náà kò jí. Nígbà tí Eliṣa dé ilé náà, ó bá òkú ọmọ náà lórí ibùsùn. Ó wọlé síbi tí òkú ọmọ náà wà, ó ti ìlẹ̀kùn, ó sì gbadura sí OLUWA. Ó nà gbalaja lé ọmọ náà lórí, ó fẹnu kò ó lẹ́nu, ó fojú kò ó lójú, ó sì gbé ọwọ́ lé ọwọ́ rẹ̀. Bí ó sì ti nà lé ọmọ náà, ara ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí lọ́ wọ́ọ́rọ́. Lẹ́yìn náà, ó dìde, ó rìn síwá sẹ́yìn ninu ilé náà, ó tún pada lọ nà lé ọmọ náà. Ọmọ náà sín lẹẹmeje, ó sì la ojú rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó wí fún Gehasi pé kí ó pe obinrin ará Ṣunemu náà wá, Gehasi bá pè é. Nígbà tí obinrin náà dé, Eliṣa wí fún un pé kí ó gba ọmọ rẹ̀. Obinrin náà wólẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì dojúbolẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó mú ọmọ rẹ̀, ó sì jáde lọ. Eliṣa dé sí Giligali nígbà tí ìyàn wà ní ilẹ̀ náà. Bí àwọn ọmọ wolii ti jókòó níwájú rẹ̀, ó sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó ní, “Ẹ gbé ìkòkò ńlá léná kí ẹ sì se àsáró fún àwọn ọmọ wolii.” Ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ náà lọ sí oko láti já ewébẹ̀, ó rí àjàrà tí ó máa ń hù ninu igbó, ó sì ká ninu èso rẹ̀. Nígbà tí ó dé ilé, ó rẹ́ wọn sinu ìkòkò àsáró náà láìmọ̀ ohun tí wọ́n jẹ́. Wọ́n bu oúnjẹ fún àwọn ọmọ wolii láti jẹ. Bí wọ́n ti ń jẹ àsáró náà, wọ́n kígbe pé “Eniyan Ọlọrun, májèlé wà ninu ìkòkò yìí!” Wọn kò sì lè jẹ ẹ́ mọ́. Eliṣa dáhùn, ó ní, “Ẹ bu oúnjẹ díẹ̀ wá.” Ó da oúnjẹ náà sinu ìkòkò, ó sì wí pé, “Bu oúnjẹ fún àwọn ọkunrin náà, kí wọ́n lè jẹun.” Kò sì sí oró májèlé ninu oúnjẹ náà mọ́. Ọkunrin kan wá láti Baaliṣaliṣa, ó mú burẹdi àkọ́so èso wá fún eniyan Ọlọrun, ati ogún burẹdi tí a fi ọkà-baali ṣe ati ṣiiri ọkà tuntun ninu àpò rẹ̀. Eliṣa bá wí pé, “Ẹ kó wọn fún àwọn ọmọkunrin, kí wọ́n jẹ ẹ́.” Ṣugbọn iranṣẹ rẹ̀ wí pé, “Báwo ni n óo ṣe wá gbé èyí kalẹ̀ níwájú ọgọrun-un eniyan láti jẹ?” Eliṣa tún ní, “Kó wọn fún àwọn ọmọkunrin kí wọ́n jẹ ẹ́, nítorí pé OLUWA ní, ‘Wọn yóo jẹ, yóo sì ṣẹ́kù.’ ” Iranṣẹ náà bá gbé oúnjẹ náà kalẹ̀ níwájú àwọn ọmọkunrin náà, wọ́n jẹ, ó sì ṣẹ́kù gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA. Naamani, olórí ogun Siria, jẹ́ eniyan pataki ati ọlọ́lá níwájú ọba Siria, nítorí pé nípasẹ̀ rẹ̀ ni OLUWA ṣe fún ilẹ̀ Siria ní ìṣẹ́gun. Ó jẹ́ akọni jagunjagun, ṣugbọn adẹ́tẹ̀ ni. Iyawo Naamani ní iranṣẹbinrin kékeré kan tí àwọn ará Siria mú lẹ́rú wá láti ilẹ̀ Israẹli, nígbà tí wọ́n lọ bá wọn jagun. Ní ọjọ́ kan, ọmọbinrin náà sọ fún ọ̀gá rẹ̀ pé, “Bí oluwa mi Naamani bá lọ sí ọ̀dọ̀ wolii tí ó wà ní Samaria, yóo rí ìwòsàn gbà.” Nígbà tí Naamani gbọ́, ó sọ ohun tí ọmọbinrin náà sọ fún ọba. Ọba Siria dáhùn pé, “Tètè lọ, n óo sì fi ìwé ranṣẹ sí ọba Israẹli.” Naamani mú ìwọ̀n talẹnti fadaka mẹ́wàá ati ẹgbaata (6,000) ìwọ̀n ṣekeli wúrà ati ìpààrọ̀ aṣọ mẹ́wàá, ó bá lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Israẹli pẹlu ìwé náà. Ohun tí wọ́n kọ sinu ìwé náà nìyí, “Ẹni tí ó mú ìwé yìí wá ni Naamani, iranṣẹ mi, mo rán an wá sọ́dọ̀ rẹ kí o lè wò ó sàn ninu àrùn ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.” Nígbà tí ọba Israẹli ka ìwé náà ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbẹ̀rù rẹ̀ hàn, ó sì wí pé, “Èmi ha í ṣe Ọlọrun tí ó ní agbára ikú ati ìyè bí, tí ọba Siria fi rò wí pé mo lè wo eniyan sàn kúrò ninu ẹ̀tẹ̀? Èyí fi hàn pé ó ń wá ìjà ni.” Nígbà tí Eliṣa gbọ́ pé ọba Israẹli ti fa aṣọ rẹ̀ ya, ó ranṣẹ sí i pé, “Kí ló dé tí o fi fa aṣọ rẹ ya? Mú ọkunrin náà wá sọ́dọ̀ mi, kí ó lè mọ̀ pé wolii kan wà ní Israẹli.” Naamani bá lọ ti òun ti àwọn ẹṣin ati kẹ̀kẹ́-ogun rẹ̀, ó sì dúró lẹ́nu ọ̀nà ilé Eliṣa. Eliṣa rán iranṣẹ kan kí ó sọ fún un pé kí ó lọ wẹ ara rẹ̀ ninu odò Jọdani ní ìgbà meje, yóo sì rí ìwòsàn. Ṣugbọn Naamani fi ibinu kúrò níbẹ̀, ó ní, “Mo rò pé yóo jáde wá, yóo gbadura sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀, yóo fi ọwọ́ rẹ̀ pa ibẹ̀, yóo sì ṣe àwòtán ẹ̀tẹ̀ náà ni. Ṣé àwọn odò Abana ati odò Faripari tí wọ́n wà ní Damasku kò dára ju gbogbo àwọn odò tí wọ́n wà ní Israẹli lọ ni? Ṣebí mo lè wẹ̀ ninu wọn kí n sì mọ́!” Ó bá yipada, ó ń bínú lọ. Àwọn iranṣẹ rẹ̀ bá gbà á níyànjú pé, “Baba, ṣé bí wolii náà bá sọ pé kí o ṣe ohun tí ó le ju èyí lọ, ṣé o kò ní ṣe é? Kí ló dé tí o kò lè wẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, kí o sì rí ìwòsàn gbà?” Naamani bá lọ sí odò Jọdani, ó wẹ̀ ní ìgbà meje gẹ́gẹ́ bí Eliṣa ti pàṣẹ fún un, ó rí ìwòsàn, ara rẹ̀ sì jọ̀lọ̀ bí ara ọmọde. Lẹ́yìn náà ó pada pẹlu àwọn iranṣẹ rẹ̀ sọ́dọ̀ Eliṣa, ó ní, “Nisinsinyii ni mo mọ̀ pé kò sí ọlọrun mìíràn ní gbogbo ayé àfi Ọlọrun Israẹli. Nítorí náà jọ̀wọ́ gba ẹ̀bùn yìí lọ́wọ́ iranṣẹ rẹ.” Ṣugbọn Eliṣa dáhùn pé, “Mo fi OLUWA tí mò ń sìn búra pé n kò ní gba nǹkankan lọ́wọ́ rẹ.” Naamani rọ̀ ọ́ kí ó gbà wọ́n, ṣugbọn ó kọ̀. Naamani bá ní, “Jọ̀wọ́ fún mi ní ààyè láti bu erùpẹ̀ ẹrù kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ meji lọ sílé nítorí láti òní lọ, iranṣẹ rẹ kì yóo rúbọ sí ọlọrun mìíràn bíkòṣe OLUWA. Mo bẹ̀bẹ̀ kí OLUWA dáríjì mí nígbà tí mo bá tẹ̀lé oluwa mi lọ sinu tẹmpili Rimoni, oriṣa Siria láti rúbọ sí i. Bí oluwa mi bá gbé ara lé apá mi, tí èmi náà sì tẹríba ninu tẹmpili Rimoni, kí OLUWA dáríjì iranṣẹ rẹ.” Eliṣa sọ fún un pé “Máa lọ ní alaafia.” Naamani bá lọ. Ṣugbọn kò tíì rìn jìnnà, nígbà tí Gehasi, iranṣẹ Eliṣa, sọ ninu ara rẹ̀ pé, “Olúwa mi jẹ́ kí Naamani ará Siria yìí lọ láì gba ohun tí ó mú wá lọ́wọ́ rẹ̀. Mo fi OLUWA búra pé, n óo sáré tẹ̀lé e láti gba nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀.” Ó bá sáré tẹ̀lé Naamani. Nígbà tí Naamani rí i pé ẹnìkan ń sáré bọ̀, ó sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ ogun tí ó gùn láti pàdé rẹ̀, ó bèèrè pé, “Ṣé kò sí nǹkan?” Gehasi dáhùn pé, “Rárá, kò sí nǹkan. Oluwa mi ni ó rán mi sí ọ pé, ‘Nisinsinyii ni meji ninu àwọn ọmọ àwọn wolii tí wọn ń gbé òkè Efuraimu wá sọ́dọ̀ mi. Jọ̀wọ́ fún wọn ní ìwọ̀n talẹnti fadaka kan ati aṣọ meji.’ ” Naamani sì rọ̀ ọ́ kí ó gba ìwọ̀n talẹnti meji. Ó di owó náà sinu àpò meji pẹlu aṣọ meji. Ó pàṣẹ fún iranṣẹ meji kí wọ́n bá Gehasi gbé wọn lọ. Nígbà tí wọ́n dé orí òkè tí Eliṣa ń gbé, Gehasi gba àwọn ẹrù náà lórí wọn, ó gbé wọn sinu ilé, ó sì dá àwọn iranṣẹ Naamani pada. Nígbà tí ó wọlé, Eliṣa bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Níbo ni o lọ?” Ó dáhùn pé, “N kò lọ sí ibìkan kan.” Eliṣa dáhùn pé, “Ṣé o kò mọ̀ pé mo wà pẹlu rẹ ninu ẹ̀mí, nígbà tí Naamani sọ̀kalẹ̀ ninu kẹ̀kẹ́-ogun, tí ó gùn, tí ó wá láti pàdé rẹ? Ṣé àkókò yìí ni ó yẹ láti gba fadaka tabi aṣọ tabi olifi tabi ọgbà àjàrà tabi aguntan tabi mààlúù tabi iranṣẹkunrin tabi iranṣẹbinrin? Nítorí ìdí èyí, ẹ̀tẹ̀ Naamani yóo lẹ̀ mọ́ ọ lára ati ìdílé rẹ ati ìrandíran rẹ títí lae.” Gehasi sì jáde kúrò lọ́dọ̀ Eliṣa ní adẹ́tẹ̀, ó funfun bíi ẹ̀gbọ̀n òwú. Ní ọjọ́ kan àwọn ọmọ àwọn wolii tí wọ́n wà lábẹ́ àkóso Eliṣa sọ fún un pé, “Ibi tí à ń gbé kéré jù fún wa. Jọ̀wọ́ fún wa ní ààyè láti lọ gé igi ní etí odò Jọdani láti fi kọ́ ilé mìíràn tí a óo máa gbé.” Eliṣa dáhùn pé, “Ó dára, ẹ máa lọ.” Ọ̀kan ninu wọn bẹ̀ ẹ́ pé kí ó bá àwọn lọ, ó sì gbà bẹ́ẹ̀. Gbogbo wọn jọ lọ, nígbà tí wọ́n dé etí odò Jọdani, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gé igi. Bí ọ̀kan ninu wọn ti ń gé igi, lójijì, irin àáké tí ó ń lò yọ bọ́ sinu odò. Ó kígbe pé, “Yéè! Oluwa mi, a yá àáké yìí ni!” Eliṣa bèèrè pé, “Níbo ni ó bọ́ sí?” Ọkunrin náà sì fi ibẹ̀ hàn án. Eliṣa gé igi kan, ó jù ú sinu omi, irin àáké náà sì léfòó lójú omi. Eliṣa pàṣẹ fún un pé, “Mú un.” Ọkunrin náà bá mu irin àáké náà. Ní ìgbà kan tí ọba Siria ń bá ọba Israẹli jagun, ó bá àwọn olórí ogun rẹ̀ gbèrò ibi tí wọn yóo ba sí de àwọn ọmọ ogun Israẹli. Eliṣa ranṣẹ sí ọba Israẹli pé kí ó má ṣe gba ibẹ̀ nítorí pé àwọn ará Siria ba sibẹ. Ọba Israẹli bá ranṣẹ sí àwọn eniyan tí ń gbé ibi tí Eliṣa kilọ̀ fún un nípa rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ níí máa ń kìlọ̀ fún ọba Israẹli tí ọba Israẹli sì ń bọ́ kúrò ninu tàkúté ọba Siria. Ó ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní ọpọlọpọ ìgbà. Ọkàn ọba Siria kò balẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ yìí, nítorí náà, ó pe gbogbo àwọn olórí ogun rẹ̀ jọ, ó sì bi wọ́n pé, “Ta ló ń tú àṣírí wa fún ọba Israẹli ninu yín?” Ọ̀kan ninu wọn dáhùn pé, “Kò sí ẹnìkan ninu wa tí ń sọ àṣírí fún ọba Israẹli. Wolii Eliṣa ní ń sọ fún un, títí kan gbogbo ohun tí ẹ bá sọ ní kọ̀rọ̀ yàrá yín.” Ọba bá pàṣẹ pé, “Ẹ lọ wádìí ibi tí ó ń gbé, kí n lè ranṣẹ lọ mú un.” Nígbà tí wọ́n sọ fún un pé Eliṣa wà ní Dotani, ó rán ọpọlọpọ àwọn ọmọ ogun ati ẹṣin ati kẹ̀kẹ́-ogun lọ sibẹ. Ní òru ni wọ́n dé ìlú náà, wọ́n sì yí i po. Ní òwúrọ̀ kutukutu, nígbà tí iranṣẹ Eliṣa jáde sí ìta, ó rí i pé àwọn ọmọ ogun Siria ti yí ìlú náà po pẹlu ẹṣin ati àwọn kẹ̀kẹ́-ogun. Ó pada wọlé tọ Eliṣa lọ, ó sì kígbe pé, “Yéè, oluwa mi, kí ni a óo ṣe?” Eliṣa dáhùn pé, “Má bẹ̀rù nítorí pé àwọn tí wọ́n wà pẹlu wa ju àwọn tí wọ́n wà pẹlu wọn lọ.” Eliṣa bá gbadura pé kí OLUWA jọ̀wọ́ ṣí ojú rẹ̀, kí ó lè ríran. OLUWA ṣí iranṣẹ náà lójú, ó sì rí i pé gbogbo orí òkè náà kún fún ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun, iná sí yí Eliṣa ká. Nígbà tí àwọn ará Siria gbìyànjú láti mú un, ó gbadura pé kí OLUWA jọ̀wọ́ fọ́ àwọn ọkunrin náà lójú. OLUWA sì fọ́ wọn lójú gẹ́gẹ́ bí adura Eliṣa. Eliṣa tọ̀ wọ́n lọ, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ ti ṣìnà; èyí kì í ṣe ìlú tí ẹ̀ ń wá, ẹ tẹ̀lé mi n óo fi ẹni tí ẹ̀ ń wá hàn yín.” Ó sì mú wọn lọ sí Samaria. Ní kété tí wọ́n wọ Samaria, Eliṣa gbadura pé kí OLUWA ṣí wọn lójú kí wọ́n lè ríran. OLUWA sì ṣí wọn lójú, wọ́n rí i pé ààrin Samaria ni àwọn wà. Nígbà tí ọba Israẹli rí wọn, ó bi Eliṣa pé, “Ṣé kí n pa wọ́n, oluwa mi, ṣé kí n pa wọ́n?” Eliṣa dáhùn pé, “O kò gbọdọ̀ pa wọ́n, ṣé o máa pa àwọn tí o bá kó lójú ogun ni? Gbé oúnjẹ ati omi kalẹ̀ níwájú wọn, kí wọ́n jẹ, kí wọ́n mu, kí wọ́n sì pada sọ́dọ̀ oluwa wọn.” Nítorí náà, ọba Israẹli pèsè oúnjẹ fún wọn lọpọlọpọ. Lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹ, tí wọ́n sì ti mu, wọ́n pada sọ́dọ̀ oluwa wọn. Láti ọjọ́ náà ni àwọn ọmọ ogun Siria kò ti gbógun ti ilẹ̀ Israẹli mọ́. Lẹ́yìn èyí, Benhadadi, ọba Siria, kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ láti bá Israẹli jagun, wọ́n sì dóti ìlú Samaria. Nítorí náà, ìyàn ńlá mú ní ìlú náà tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ń ta orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní ọgọrin ìwọ̀n ṣekeli fadaka ati idamẹrin òṣùnwọ̀n kabu ìgbẹ́ ẹyẹlé ní ìwọ̀n ṣekeli fadaka marun-un. Bí ọba Israẹli ti ń rìn lórí odi ìlú, obinrin kan kígbe pè é, ó ní, “Olúwa mi, ọba, ràn mí lọ́wọ́.” Ọba dáhùn pé, “Bí OLUWA kò bá ràn ọ́ lọ́wọ́, ìrànlọ́wọ́ wo ni èmi lè ṣe? Ṣé mo ní ìyẹ̀fun tabi ọtí waini ni?” Ó bá bèèrè pé, “Kí ni ìṣòro rẹ?” Obinrin náà dáhùn, ó ní, “Obinrin yìí sọ fún mi pé kí n mú ọmọ mi wá kí á pa á jẹ, bí ó bá di ọjọ́ keji a óo pa ọmọ tirẹ̀ jẹ, ni a bá pa ọmọ tèmi jẹ. Ní ọjọ́ keji, mo sọ fún un pé kí ó mú ọmọ tirẹ̀ wá kí á pa á jẹ, ṣugbọn ó fi ọmọ tirẹ̀ pamọ́.” Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn. Àwọn tí wọ́n wà lẹ́bàá odi níbi tí ó ń gbà lọ sì rí i pé ó wọ aṣọ-ọ̀fọ̀ sí abẹ́ aṣọ rẹ̀. Ó sì búra pé kí OLUWA ṣe jù bẹ́ẹ̀ sí òun bí òun kò bá gé orí Eliṣa, ọmọ Ṣafati, kí ilẹ̀ ọjọ́ náà tó ṣú. Eliṣa jókòó ninu ilé rẹ̀ pẹlu àwọn alàgbà. Ọba rán ọkunrin kan ṣáájú láti lọ pa á, ṣugbọn Eliṣa sọ fún àwọn alàgbà tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Wò ó, ọmọ apànìyàn yìí ti rán ẹnìkan láti wá pa mí, ọba fúnra rẹ̀ sì ń tẹ̀lé e bọ̀ lẹ́yìn. Bí iranṣẹ náà bá dé, ẹ ti ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà kí ó má lè wọlé.” Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni ọba dé, ó ní, “Láti ọ̀dọ̀ OLUWA ni ibi yìí ti wá, kí ló dé tí n óo fi tún máa dúró de OLUWA fún ìrànlọ́wọ́?” Eliṣa dáhùn pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ní àkókò yìí lọ́la, ní ẹnubodè Samaria, àwọn eniyan yóo ra òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná kan, tabi òṣùnwọ̀n ọkà baali meji ní ìwọ̀n ṣekeli kan.” Ọ̀kan ninu àwọn ọ̀gágun tí wọ́n wà níbẹ̀, tí ó jẹ́ aṣojú ọba dá Eliṣa lóhùn, ó ní, “Bí OLUWA bá tilẹ̀ da àwọn nǹkan wọnyi sílẹ̀ láti ojú ọ̀run wá, ǹjẹ́ ohun tí o sọ yìí lè rí bẹ́ẹ̀?” Eliṣa dá a lóhùn pé, “O óo fi ojú rí i, ṣugbọn o kò ní jẹ ninu rẹ̀.” Àwọn adẹ́tẹ̀ mẹrin kan wà ní ẹnubodè Samaria, wọ́n sọ fún ara wọn pé, “Kí ló dé tí a óo fi dúró síbí títí tí a óo fi kú? Bí a bá lọ sinu ìlú ebi yóo pa wá kú nítorí ìyàn wà níbẹ̀, bí a bá sì dúró níbí, a óo kú bákan náà. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á lọ sí ibùdó ogun àwọn ará Siria. Bí wọ́n bá pa wá, a jẹ́ pé ikú yá, bí wọ́n bá sì dá wa sí, a óo wà láàyè.” Nígbà tí ọjọ́ bẹ̀rẹ̀ sí pofírí, wọ́n lọ sí ibùdó ogun àwọn ará Siria, nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, wọn kò rí ẹnìkan kan. OLUWA ti mú kí àwọn ọmọ ogun Siria gbọ́ ìró ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun ati ẹṣin ati ọpọlọpọ àwọn ọmọ ogun. Wọ́n wí fún ara wọn pé ọba Israẹli ti lọ bẹ àwọn ọmọ ogun Hiti ati ti Ijipti láti wá bá àwọn jà. Nítorí náà, wọ́n sá lọ ní àṣáálẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n fi ibùdó ogun wọn ati àwọn ẹṣin wọn ati àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn sílẹ̀, wọ́n sì sá àsálà fún ẹ̀mí wọn. Nígbà tí àwọn adẹ́tẹ̀ mẹrin náà dé ìkangun ibùdó ogun, wọ́n wọ inú àgọ́ kan lọ. Wọ́n jẹ ohun tí wọ́n bá níbẹ̀; wọ́n sì mu. Wọ́n kó fadaka ati wúrà ati aṣọ tí wọ́n rí níbẹ̀, wọ́n lọ kó wọn pamọ́. Wọ́n pada wá, wọ́n wọ inú àgọ́ mìíràn, wọ́n tún ṣe bákan náà. Lẹ́yìn náà, wọ́n sọ fún ara wọn pé, “Ohun tí à ń ṣe yìí kò dára, ọjọ́ ìròyìn ayọ̀ ni ọjọ́ òní. Bí a bá dákẹ́, tí a sì dúró di òwúrọ̀ a óo jìyà. Ẹ jẹ́ kí á lọ sọ fún àwọn ará ilé ọba.” Wọ́n bá lọ sí Samaria, wọ́n sì kígbe pe àwọn aṣọ́nà láti ẹnubodè pé, “A ti lọ sí ibùdó ogun àwọn ará Siria, a kò rí ẹnìkan kan níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kò gbúròó ẹnìkan kan. Àwọn ẹṣin ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn wà bí wọ́n ṣe so wọ́n mọ́lẹ̀, gbogbo àwọn àgọ́ wọn sì wà gẹ́gẹ́ bí àwọn ará Siria ti fi wọ́n sílẹ̀.” Àwọn aṣọ́nà bá sọ fún àwọn tí wọ́n wà ní ààfin ọba. Ọba dìde ní òru ọjọ́ náà, ó sọ fún àwọn olórí ogun rẹ̀ pé, “Mo mọ ète àwọn ará Siria. Wọ́n mọ̀ pé ìyàn mú ninu ìlú wa, nítorí náà ni wọ́n ṣe fi ibùdó ogun wọn sílẹ̀ láti sá pamọ́ sinu igbó, pẹlu èrò pé a óo wá oúnjẹ wá. Kí wọ́n lè mú wa láàyè, kí wọ́n sì gba ìlú wa.” Ọ̀kan ninu àwọn olórí ogun náà dá ọba lóhùn pé, “Ṣebí àwọn eniyan náà yóo kú ni gẹ́gẹ́ bí àwọn tí wọ́n ti kú. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á rán àwọn ọkunrin kan pẹlu ẹṣin marun-un tí ó kù láti lọ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀.” Ọba sì rán ọkunrin meji pẹlu kẹ̀kẹ́ ogun meji láti lọ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Àwọn ọkunrin náà lọ títí dé odò Jọdani. Ní gbogbo ojú ọ̀nà náà ni wọ́n ti ń rí àwọn aṣọ ati àwọn ohun ìjà tí àwọn ará Siria jù sọnù nígbà tí wọn ń sá lọ. Wọ́n sì pada wá ròyìn fún ọba. Àwọn ará Samaria sì tú jáde láti lọ kó ìkógun ní ibùdó ogun àwọn ará Siria. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí OLUWA ti sọ, wọ́n ta òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná kan ní ìwọ̀n ṣekeli kan. Ọba Israẹli fi ìtọ́jú ẹnubodè ìlú sí abẹ́ àkóso ọ̀gágun tí ó jẹ́ aṣojú rẹ̀. Àwọn eniyan sì tẹ ọ̀gágun náà pa, gẹ́gẹ́ bí Eliṣa ti sọtẹ́lẹ̀ nígbà tí ọba lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Nítorí nígbà tí eniyan Ọlọrun sọ fún ọba pé, “Ní ìwòyí ọ̀la, lẹ́nu bodè Samaria, àwọn eniyan yóo máa ra òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná kan tabi òṣùnwọ̀n ọkà baali meji ní ìwọ̀n ṣekeli kọ̀ọ̀kan,” ọ̀gágun náà dáhùn pé, “Ǹjẹ́ èyí lè ṣẹ, bí OLUWA tilẹ̀ rọ̀jò àwọn nǹkan wọnyi sílẹ̀ láti ojú ọ̀run wá.” Eliṣa sì dá a lóhùn pé, “O óo fi ojú rẹ rí i, ṣugbọn o kò ní jẹ ninu rẹ̀.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀ fún un, nítorí àwọn eniyan tẹ ọ̀gágun náà pa ní ẹnubodè ìlú. Eliṣa sọ fún obinrin ará Ṣunemu, ẹni tí Eliṣa jí ọmọ rẹ̀ tí ó kú pé, “OLUWA yóo rán ìyàn sí ilẹ̀ yìí fún ọdún meje, nítorí náà, kí ìwọ ati ẹbí rẹ lọ máa gbé ní ilẹ̀ mìíràn.” Obinrin náà gbọ́ ọ̀rọ̀ Eliṣa, òun ati ẹbí rẹ̀ sì lọ ń gbé ilẹ̀ àwọn ará Filistia fún ọdún meje. Lẹ́yìn ọdún keje, obinrin náà pada sí Israẹli, ó sì lọ sọ́dọ̀ ọba láti bẹ̀ ẹ́ pé kí ó dá ilé ati ilẹ̀ òun pada. Ó bá ọba tí ó ń bá Gehasi iranṣẹ Eliṣa sọ̀rọ̀; ọba fẹ́ mọ̀ nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu Eliṣa. Bí Gehasi ti ń sọ fún ọba bí Eliṣa ṣe jí òkú dìde, ni obinrin tí Eliṣa jí òkú ọmọ rẹ̀ dìde wá sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún ọba. Gehasi sọ fún ọba pé, “Olúwa mi, obinrin náà nìyí, ọmọkunrin rẹ̀ tí Eliṣa jí dìde náà sì nìyí.” Ọba bèèrè lọ́wọ́ obinrin náà, ó sì sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún ọba. Ọba bá pàṣẹ fún ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ rẹ̀ kí ó fún obinrin náà ní gbogbo ohun tíí ṣe tirẹ̀ pẹlu gbogbo ohun tí wọ́n ti kórè ninu oko náà, láti ìgbà tí obinrin náà ti fi ìlú sílẹ̀ títí di ìgbà tí ó pada dé. Eliṣa lọ sí Damasku ní àkókò kan tí Benhadadi ọba Siria wà lórí àìsàn. Nígbà tí wọ́n sọ fún ọba pé Eliṣa wà ní Damasku, ọba sọ fún Hasaeli, ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Mú ẹ̀bùn lọ́wọ́, kí o sì lọ bá wolii náà, kí o sọ fún un pé kí ó bá mi bèèrè lọ́wọ́ OLUWA bóyá n óo yè ninu àìsàn yìí.” Hasaeli di ogoji ẹrù ràkúnmí tí ó kún fún oniruuru ohun rere tí ó wà ní Damasku, ó lọ bá Eliṣa. Nígbà tí Hasaeli pàdé rẹ̀, ó sọ pé, “Iranṣẹ rẹ, Benhadadi, ọba Siria, rán mi láti bèèrè lọ́wọ́ rẹ bóyá òun óo yè ninu àìsàn òun.” Eliṣa dáhùn pé, “OLUWA ti fi hàn mí pé yóo kú, ṣugbọn lọ sọ fún un pé yóo yè.” Eliṣa tẹjú mọ́ Hasaeli títí ojú fi tì í. Eliṣa sì sọkún. Hasaeli bèèrè pé, “Kí ló dé tí o fi ń sunkún, oluwa mi?” Eliṣa dáhùn pé, “Nítorí pé mo mọ oríṣìíríṣìí nǹkan burúkú tí o óo ṣe sí àwọn ọmọ Israẹli: O óo jó ibi ààbò wọn, o óo fi idà pa àwọn ọmọkunrin wọn, o óo tú àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn ká, o óo sì la inú àwọn aboyún wọn.” Hasaeli dáhùn pé, “Ta ni mí, tí n óo fi ṣe nǹkan tí ó lágbára tóbẹ́ẹ̀?” Eliṣa dáhùn pé, “OLUWA ti fi hàn mí pé o óo jọba ní Siria.” Ó bá pada lọ sọ́dọ̀ Benhadadi, ó sì bèèrè ohun tí Eliṣa sọ lọ́wọ́ rẹ̀. Hasaeli dáhùn pé, “O óo yè ninu àìsàn rẹ.” Ní ọjọ́ keji Hasaeli mú aṣọ tí ó nípọn, ó rì í bọ omi, ó sì fi bo ojú Benhadadi títí ó fi kú. Hasaeli sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Ní ọdún karun-un tí Joramu ọmọ Ahabu jọba ní Israẹli, ni Jehoramu ọmọ Jehoṣafati jọba ní ilẹ̀ Juda. Ẹni ọdún mejilelọgbọn ni, nígbà tí ó jọba, ó sì jọba fún ọdún mẹjọ. Ó tẹ̀ sí ọ̀nà àwọn ọba Israẹli gẹ́gẹ́ bí ilé Ahabu nítorí ọmọ Ahabu, ni iyawo rẹ̀, ó ṣe ibi níwájú OLUWA. Sibẹsibẹ OLUWA kò pa Juda run nítorí ó ti búra fún Dafidi iranṣẹ rẹ̀ pé ìran rẹ̀ yóo máa jọba ní ilẹ̀ Juda. Ní àkókò ìjọba Jehoramu, Edomu ṣọ̀tẹ̀ sí Juda, wọ́n sì yan ọba fún ara wọn. Nítorí náà, Jehoramu kó gbogbo àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, wọ́n lọ sí Sairi láti bá Edomu jagun. Níbẹ̀ ni àwọn ọmọ ogun Edomu ti yí wọn ká. Ní òru, òun ati àwọn olórí ogun rẹ̀ kọlu àwọn ará Edomu tí wọ́n yí wọn ká, wọ́n sì sá àsálà, ṣugbọn àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sá pada sí ilé wọn. Láti ìgbà náà ni Edomu ti di òmìnira kúrò lọ́wọ́ Juda. Ní àkókò kan náà ni ìlú Libina ṣọ̀tẹ̀ sí Juda. Gbogbo àwọn nǹkan yòókù tí Jehoramu ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. Jehoramu kú, wọ́n sì sin ín sí ibojì àwọn ọba ní ìlú Dafidi. Ahasaya ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Ní ọdún kejila tí Joramu ọmọ Ahabu ti jọba ní Israẹli ni Ahasaya, ọmọ Jehoramu, jọba ní ilẹ̀ Juda. Ẹni ọdún mejilelogun ni nígbà tí ó jọba ni Jerusalẹmu, ó sì jọba fún ọdún kan. Atalaya ni ìyá rẹ̀, ọmọ Omiri, ọba ilẹ̀ Israẹli. Ọ̀nà ìdílé Ahabu ọba ni Ahasaya tẹ̀ sí, ó sì ṣe burúkú níwájú OLUWA, bí ìdílé Ahabu ti ṣe; nítorí pé àna ló jẹ́ fún Ahabu. Ahasaya bá Joramu, ọba Israẹli lọ, wọ́n gbógun ti Hasaeli, ọba Siria, ní Ramoti Gileadi. Àwọn ọmọ ogun Siria ṣá ọba Joramu lọ́gbẹ́. Ó pada sí ìlú Jesireeli, ó lọ wo ọgbẹ́ náà sàn. Ahasaya, ọba Juda, ọmọ Jehoramu, sì lọ bẹ̀ ẹ́ wò ní Jesireeli. Eliṣa pe ọ̀kan ninu àwọn ọmọ àwọn wolii, ó sọ fún un pé, “Ṣe kánkán, kí o lọ sí Ramoti Gileadi pẹlu ìgò òróró yìí. Nígbà tí o bá dé ibẹ̀, bèèrè Jehu, ọmọ Jehoṣafati, ọmọ Nimṣi; mú un wọ yàrá kan lọ kúrò láàrin àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀. Kí o da òróró inú ìgò yìí sí i lórí, kí o sì wí pé, OLUWA sọ pé, ‘Mo fi òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli.’ Kí o sì yára sá kúrò níbẹ̀.” Ọdọmọkunrin wolii náà bá lọ sí Ramoti Gileadi. Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó bá àwọn olórí ogun níbi tí wọ́n ti ń ṣe ìpàdé. Ó wí pé, “Balogun, wọ́n rán mi níṣẹ́ sí ọ.” Jehu bá bèèrè pé, “Ta ni ninu wa?” Ọdọmọkunrin náà bá dáhùn pé, “Ìwọ ni, Balogun.” Àwọn mejeeji bá jọ wọ inú yàrá lọ, ọdọmọkunrin wolii náà da òróró sí orí Jehu, ó sì wí pé, “Báyìí ni OLUWA Ọlọrun Israẹli wí, ‘Mo fi òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli, àwọn eniyan OLUWA.’ O óo pa ìdílé oluwa rẹ, Ahabu ọba rẹ́, kí n lè gbẹ̀san lára Jesebẹli fún àwọn wolii mi ati àwọn iranṣẹ mi tí ó pa. Gbogbo ìdílé Ahabu ni yóo ṣègbé, n óo sì pa gbogbo àwọn ọmọkunrin tí wọ́n wà ninu ìdílé náà, ati ẹrú ati ọmọ. N óo ṣe ìdílé Ahabu bí mo ti ṣe àwọn ìdílé Jeroboamu ọmọ Nebati, ati ìdílé Baaṣa ọba, ọmọ Ahija. Ajá ni yóo jẹ òkú Jesebẹli ní agbègbè Jesireeli, kò sí ẹni tí yóo sin òkú rẹ̀.” Lẹ́yìn tí ó ti sọ̀rọ̀ náà tán, ó ṣí ìlẹ̀kùn, ó sá lọ. Nígbà tí Jehu pada sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀, wọ́n bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé kò sí nǹkan? Kí ni ọkunrin bíi wèrè yìí ń wá lọ́dọ̀ rẹ?” Jehu dáhùn pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ ọkunrin náà, ati ohun tí ó sọ?” Wọ́n dáhùn pé, “Rárá, a kò mọ̀ ọ́n, sọ fún wa.” Jehu sì dáhùn pé, “Ó sọ fún mi pé OLUWA ti fi òróró yàn mí ní ọba lórí Israẹli.” Lẹ́sẹ̀ kan náà, àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ tẹ́ aṣọ wọn sílẹ̀ fún un kí ó dúró lé, wọ́n sì fun fèrè pé, “Kabiyesi, Jehu ọba!” Jehu, ọmọ Jehoṣafati, ọmọ Nimṣi, dìtẹ̀ mọ́ Joramu. (Ní àkókò yìí Joramu ati àwọn ọmọ ogun Israẹli ń ṣọ́ Hasaeli ọba Siria ní Ramoti Gileadi; ṣugbọn Joramu ọba ti lọ sí Jesireeli láti tọ́jú ọgbẹ́ tí wọ́n ṣá a lójú ogun Siria.) Jehu sọ fún àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé, “Bí ẹ bá wà lẹ́yìn mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni jáde kúrò ní ìlú láti lọ ròyìn fún wọn ní Jesireeli.” Jehu gun kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó lọ sí Jesireeli nítorí ibẹ̀ ni Joramu ọba wà, Ahasaya, ọba Juda sì wá bẹ̀ ẹ́ wò níbẹ̀. Ọ̀kan ninu àwọn aṣọ́nà tí ó wà ninu ilé ìṣọ́ ní Jesireeli rí i tí Jehu ati àwọn ọkunrin rẹ̀ ń bọ̀. Ó sì kígbe pé, “Mo rí àwọn ọkunrin kan tí wọ́n ń gun kẹ̀kẹ́ ogun bọ̀.” Joramu dáhùn pé, “Rán ẹlẹ́ṣin kan láti bèèrè bóyá alaafia ni.” Ẹlẹ́ṣin kan lọ pàdé rẹ̀, ó ní, “Ọba wí pé, ṣé alaafia ni?” Jehu dá a lóhùn pé, “Kí ni o ní ṣe pẹlu alaafia? Bọ́ sẹ́yìn mi.” Olùṣọ́ náà wí pé, “Oníṣẹ́ náà dé ọ̀dọ̀ wọn ṣugbọn kò pada wá.” Wọ́n bá tún rán oníṣẹ́ mìíràn lọ láti bèèrè ìbéèrè kan náà lọ́wọ́ Jehu. Ó tún dáhùn pé “Kí ni o fẹ́ fi alaafia ṣe? Bọ́ sẹ́yìn mi.” Olùṣọ́ bá tún jíṣẹ́ fun ọba pé, “Oníṣẹ́ náà dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣugbọn kò pada.” Ó tún fi kún un pé, “Wọ́n ń wa kẹ̀kẹ́ ogun wọn bíi Jehu, ọmọ Nimṣi, nítorí wọ́n ń wà á pẹlu ibinu.” Joramu ọba pàṣẹ pé kí wọ́n gbé kẹ̀kẹ́ ogun òun wá, wọ́n sì gbé e wá fún un. Joramu ọba ati Ahasaya, ọba Juda sì jáde lọ pàdé Jehu, olukuluku ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀. Wọ́n pàdé rẹ̀ ninu oko Naboti ara Jesireeli. Joramu bèèrè pé, “Ṣé alaafia ni?” Jehu dáhùn pé, “Alaafia ṣe lè wà níwọ̀n ìgbà tí ìwà àgbèrè ati àjẹ́ ìyá rẹ ṣì wà sibẹ.” Joramu bá kígbe pé, “Ọ̀tẹ̀ nìyí, Ahasaya!” Ó yí kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ pada, ó ń sá lọ. Jehu fi gbogbo agbára ta ọfà rẹ̀, ó bá Joramu lẹ́yìn, ó wọ inú ọkàn rẹ̀ lọ, Joramu sì kú sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀. Jehu sọ fún Bidikari, ẹni tí ń ru ihamọra rẹ̀, ó ní, “Gbé òkú rẹ̀ kí o jù ú sinu oko Naboti. Ṣé o ranti pé, nígbà tí èmi pẹlu rẹ ń gun kẹ̀kẹ́ ogun lẹ́yìn Ahabu baba rẹ̀, OLUWA sọ ọ̀rọ̀ wọnyi nípa Ahabu, pé, ‘Mo rí i bí o ti pa Naboti ati àwọn ọmọ rẹ̀ lánàá, dájúdájú n óo jẹ ọ́ níyà ninu oko kan náà.’ Nítorí náà gbé òkú rẹ̀ jù sinu oko Naboti gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA.” Nígbà tí Ahasaya rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó sá gba ọ̀nà Beti Hagani lọ. Jehu bẹ̀rẹ̀ sí lépa rẹ̀, ó pàṣẹ fún àwọn ọkunrin rẹ̀ pé kí wọ́n ta á lọ́fà! Wọ́n sì ta á lọ́fà ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ní ọ̀nà Guri lẹ́bàá Ibileamu, ó sá lọ sí Megido, níbẹ̀ ni ó sì kú sí. Àwọn olórí ogun rẹ̀ gbé òkú rẹ̀ sinu kẹ̀kẹ́ ogun kan lọ sí Jerusalẹmu. Wọ́n sin ín sinu ibojì àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Ahasaya jọba ní ilẹ̀ Juda ní ọdún kọkanla tí Joramu ọmọ Ahabu ti jọba ní Israẹli. Nígbà tí Jehu dé Jesireeli, Jesebẹli gbọ́; ó lé tìróò, ó di irun rẹ̀, ó sì ń yọjú wo ìta láti ojú fèrèsé ní òkè. Bí Jehu ti gba ẹnu ọ̀nà wọlé, Jesebẹli kígbe pé, “Ṣé alaafia ni, Simiri? Ìwọ tí o pa oluwa rẹ!” Jehu bá gbé ojú rẹ̀ sókè, ó ní, “Ta ló wà lẹ́yìn mi ninu yín?” Àwọn ìwẹ̀fà meji tabi mẹta sì yọjú sí i láti ojú fèrèsé. Jehu bá ké sí wọn, ó ni, “Ẹ Jù ú sílẹ̀.” Wọ́n bá ju Jesebẹli sí ìsàlẹ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì ta sí ara ògiri ati sí ara àwọn ẹṣin, àwọn ẹṣin Jehu sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ kọjá. Lẹ́yìn náà, ó wọlé, ó jẹ, ó mu, lẹ́yìn náà, ó ní, “Ẹ lọ sin òkú obinrin ẹni ègún yìí nítorí pé ọmọ ọba ni.” Àwọn ọkunrin tí wọ́n lọ sin òkú náà kò rí nǹkankan àfi agbárí, ati egungun ọwọ́ ati ti ẹsẹ̀ rẹ̀. Nígbà tí wọ́n pada wá sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Jehu, ó ní, “OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu wolii Elija, iranṣẹ rẹ̀ pé, ajá ni yóo jẹ òkú Jesebẹli ní agbègbè Jesireeli. Òkú rẹ̀ yóo fọ́n ká bí ìgbẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ní lè dá a mọ̀ mọ́.” Ahabu ní aadọrin ọmọkunrin tí wọn ń gbé Samaria. Jehu kọ ìwé ranṣẹ sí àwọn olórí ìlú ati àwọn àgbààgbà ati àwọn olùtọ́jú àwọn ọmọ Ahabu, ó ní: “Ẹ̀yin ni ẹ̀ ń ṣe àkóso àwọn ọmọ ọba, ẹ sì ní àwọn kẹ̀kẹ́ ogun, ẹṣin, ati àwọn ohun ìjà ati àwọn ìlú olódi ní ìkáwọ́ yín. Nítorí náà, ní kété tí ẹ bá gba ìwé yìí, ẹ fi èyí tí ó bá jẹ́ akọni jùlọ lára àwọn ọmọ ọba sí orí oyè, ẹ sì múra láti jà fún ilẹ̀ oluwa yín.” Ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, wọ́n ní, “Ǹjẹ́ àwa lè bá Jehu, ẹni tí ó ṣẹgun ọba meji jà?” Nítorí náà, ẹni tí ó ń ṣe ìtọ́jú ààfin ati olórí ìlú pẹlu àwọn àgbààgbà ati àwọn olùtọ́jú àwọn ọmọ Ahabu ranṣẹ sí Jehu, wọ́n ní: “Iranṣẹ rẹ ni wá, a sì ti ṣetán láti ṣe ohunkohun tí o bá pa láṣẹ. A kò ní fi ẹnikẹ́ni sórí oyè, ṣe ohunkohun tí o bá rò pé ó dára.” Jehu tún kọ ìwé mìíràn sí wọn, ó ní, “Bí ó bá jẹ́ pé ẹ wà lẹ́yìn mi, ẹ sì ṣetán láti tẹ̀lé àṣẹ mi, ẹ kó orí àwọn ọmọ ọba Ahabu wá fún mi ní Jesireeli ní àkókò yìí ní ọ̀la.” Àwọn aadọrin ọmọ Ahabu náà wà ní abẹ́ ìtọ́jú àwọn àgbààgbà ìlú Samaria. Nígbà tí wọ́n rí ìwé Jehu gbà, àwọn olórí Samaria pa gbogbo àwọn ọmọ Ahabu, wọ́n sì kó orí wọn sinu apẹ̀rẹ̀ lọ fún Jehu ní Jesireeli. Nígbà tí wọ́n jíṣẹ́ fún Jehu pé wọ́n ti kó orí àwọn ọmọ Ahabu dé, ó pàṣẹ pé kí wọ́n kó wọn jọ sí ọ̀nà meji ní ẹnubodè ìlú, títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, Jehu lọ sí ẹnubodè ìlú, ó sì sọ fún àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ pé, “Ẹ kò ní ẹ̀bi, èmi ni mo ṣọ̀tẹ̀ sí Joramu ọba, oluwa mi, tí mo sì pa á. Ṣugbọn ta ni ó pa àwọn wọnyi? Èyí fihàn dájú pé gbogbo ohun tí OLUWA sọ nípa ìdílé Ahabu yóo ṣẹ. OLUWA ti ṣe ohun tí ó ṣèlérí láti ẹnu Elija, wolii rẹ̀.” Jehu pa gbogbo àwọn ìbátan Ahabu tí wọn ń gbé Jesireeli ati àwọn iranṣẹ rẹ̀, ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ati àwọn alufaa; kò dá ọ̀kan ninu wọn sí. Jehu kúrò ní Jesireeli, ó ń lọ sí Samaria. Nígbà tí ó dé ibìkan tí wọ́n ń pè ní Bẹtekedi, níbi tí àwọn olùṣọ́ aguntan ti máa ń rẹ́ irun aguntan, ó pàdé àwọn ìbátan Ahasaya, ọba Juda, ó bèèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ta ni yín?” Wọ́n dáhùn pé, “Ìbátan Ahasaya ni wá. Jesireeli ni à ń lọ láti lọ kí àwọn ọmọ ọba ati àwọn ìdílé ọba.” Jehu pàṣẹ pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mú wọn láàyè. Wọ́n mú wọn láàyè, wọ́n sì pa wọ́n ní ibi kòtò tí ó wà ní Bẹtekedi. Gbogbo wọn jẹ́ mejilelogoji, kò sì dá ọ̀kankan ninu wọn sí. Jehu tún ń lọ, ó pàdé Jehonadabu, ọmọ Rekabu, tí ń bọ̀ wá pàdé rẹ̀. Lẹ́yìn tí Jehu kí i tán, ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé ọkàn rẹ mọ́ sí mi bí ọkàn mi ti mọ́ sí ọ?” Jehonadabu dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.” Jehu dáhùn, ó ní, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, fún mi ní ọwọ́ rẹ.” Ó bá na ọwọ́ sí Jehu, Jehu sì fà á sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀. Ó ní, “Tẹ̀lé mi, kí o wá wo ìtara mi fún OLUWA.” Wọ́n sì jọ gun kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ lọ sí Samaria. Nígbà tí wọ́n dé Samaria, Jehu pa gbogbo àwọn ìbátan Ahabu, kò sì fi ọ̀kankan ninu wọn sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ láti ẹnu Elija. Lẹ́yìn náà, Jehu pe gbogbo àwọn ará Samaria jọ, ó sọ fún wọn pé, “Ahabu sin oriṣa Baali díẹ̀, ṣugbọn n óo sìn ín lọpọlọpọ. Nítorí náà, ẹ pe gbogbo àwọn wolii Baali ati àwọn tí ń bọ ọ́ ati àwọn alufaa rẹ̀ wá fún mi. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe aláìwá nítorí mo fẹ́ ṣe ìrúbọ ńlá sí Baali. Ẹnikẹ́ni tí kò bá wá, pípa ni a óo pa á.” Ṣugbọn Jehu ń ṣe èyí láti rí ààyè pa gbogbo àwọn olùsìn Baali run ni. Ó pàṣẹ pé, “Ẹ ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ fún ìsìn Baali,” wọ́n sì kéde rẹ̀. Jehu ranṣẹ sí àwọn ẹlẹ́sìn Baali ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli; kò sí ẹnìkan ninu wọn tí kò wá. Gbogbo wọn lọ sinu ilé ìsìn Baali, wọ́n sì kún inú rẹ̀ títí dé ẹnu ọ̀nà kan sí ekeji. Jehu sì pàṣẹ fún ẹni tí ń tọ́jú ibi tí wọn ń kó aṣọ ìsìn pamọ́ sí pé kí ó kó wọn jáde fún àwọn tí ń bọ Baali. Lẹ́yìn èyí, Jehu ati Jehonadabu lọ sinu ilé ìsìn náà, ó ní, “Ẹ rí i dájú pé àwọn olùsìn Baali nìkan ni wọ́n wà níhìn-ín, ati pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ń sin OLUWA níbí.” Òun pẹlu Jehonadabu bá wọlé láti rú ẹbọ sísun sí Baali. Ṣugbọn Jehu ti fi ọgọrin ọkunrin yí ilé ìsìn náà po, ó sì ti pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn tí wọ́n wá jọ́sìn níbẹ̀. Ó ní ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ kí ẹnìkan lọ, pípa ni a óo pa á. Ní kété tí Jehu parí rírú ẹbọ sísun rẹ̀, ó pàṣẹ fún àwọn olùṣọ́ ati àwọn olórí ogun pé kí wọ́n wọlé, kí wọ́n sì pa gbogbo wọn; ẹnikẹ́ni kò si gbọdọ̀ jáde. Wọ́n bá wọlé, wọ́n fi idà pa gbogbo wọn, wọ́n sì wọ́ òkú wọn síta. Lẹ́yìn náà, wọ́n wọ inú ibi mímọ́ Baali lọ, wọ́n kó gbogbo àwọn ère tí wọ́n wà níbẹ̀ jáde, wọ́n sì sun wọ́n níná. Wọ́n wó àwọn ère ati ilé ìsìn Baali lulẹ̀, wọ́n sì sọ ibẹ̀ di ilé ìgbẹ́ títí di òní yìí. Bẹ́ẹ̀ ni Jehu ṣe pa ìsìn Baali run ní Israẹli. Ṣugbọn Jehu tẹ̀lé ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu, ọmọ Nebati, tí ó mú kí Israẹli bọ ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù, tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ó wà ní Bẹtẹli ati Dani. OLUWA sọ fún Jehu pé, “Níwọ̀n ìgbà tí o ti ṣe èyí tí ó dára lójú mi, o ti ṣe ohun tí mo fẹ́ ṣe sí ilé Ahabu, tí o ṣe ohun tí ó wà lọ́kàn mi, àwọn ọmọ rẹ, títí dé ìran kẹrin, yóo máa jọba ní Israẹli.” Ṣugbọn Jehu kò kíyèsára kí ó fi gbogbo ọkàn rẹ̀ tẹ̀lé Òfin OLUWA Ọlọrun Israẹli; ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu tí ó mú kí Israẹli hù ni ó tẹ̀lé. Ní àkókò náà ni OLUWA bẹ̀rẹ̀ sí dín ilẹ̀ Israẹli kù. Hasaeli ọba Siria gba gbogbo àwọn agbègbè Israẹli, láti ìhà ìlà oòrùn Jọdani, gbogbo ilẹ̀ Gileadi ati ti ẹ̀yà Gadi, ẹ̀yà Reubẹni ati ẹya Manase. Láti Aroeri tí ó wà ní àfonífojì Arinoni tíí ṣe ilẹ̀ Gileadi ati ilẹ̀ Baṣani. Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehu ṣe, ati bí ó ti lágbára tó, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. Jehu kú, wọ́n sin òkú rẹ̀ sí Samaria, Jehoahasi ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Gbogbo àkókò tí Jehu fi jọba lórí Israẹli ní Samaria jẹ́ ọdún mejidinlọgbọn. Ní kété tí Atalaya, ìyá ọba Ahasaya gbọ́ nípa ikú ọmọ rẹ̀, ó pa gbogbo ìdílé ọba run. Joaṣi ọmọ Ahasaya nìkan ni kò pa nítorí pé Jehoṣeba ọmọbinrin Joramu ọba, arabinrin Ahasaya, gbé e sá lọ; ó sì fi òun ati alágbàtọ́ rẹ̀ pamọ́ sí yàrá kan ninu ilé OLUWA, kí Atalaya má baà pa á. Ó gbé e pamọ́ fún Atalaya, Atalaya kò sì rí i pa. Joaṣi wà ní ìpamọ́ ninu ilé OLUWA fún ọdún mẹfa, Atalaya sì ń jọba lórí ilẹ̀ Juda. Ṣugbọn ní ọdún keje, Jehoiada ranṣẹ pe àwọn olórí ogun tí wọn ń ṣọ́ ọba wá sí ilé OLUWA pẹlu àwọn olórí ogun tí wọn ń ṣọ́ ààfin. Ó bá wọn dá majẹmu, ó sì mú kí wọ́n búra láti fọwọsowọpọ pẹlu òun ninu ohun tí ó fẹ́ ṣe. Lẹ́yìn náà, ó fi ọmọ Ahasaya ọba hàn wọ́n. Ó pàṣẹ fún wọn pé, “Ìdámẹ́ta yín tí ó bá wá sí ibi iṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi yóo máa ṣọ́ ààfin. (Ìdámẹ́ta yóo máa ṣọ́ ẹnu ọ̀nà Suri; ìdámẹ́ta yòókù yóo máa ṣọ́ ẹnu ọ̀nà tí ó wà lẹ́yìn àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin), wọn yóo dáàbò bo ààfin. Àwọn ìpín mejeeji tí wọ́n bá ṣíwọ́ iṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi, yóo wá dúró ní ilé OLUWA láti dáàbò bo ọba. Wọn yóo dáàbò bo ọba pẹlu idà ní ọwọ́ wọn, wọn yóo sì máa bá a lọ sí ibikíbi tí ó bá ń lọ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ wọn, pípa ni kí wọ́n pa á.” Àwọn olórí ogun náà gbọ́ àṣẹ tí Jehoiada, alufaa, pa fún wọn, wọ́n sì kó àwọn ọmọ ogun wọn, tí wọ́n ṣíwọ́ iṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ati àwọn tí wọn yóo wọ iṣẹ́ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Jehoiada bá fún àwọn olórí ogun náà ní àwọn ọ̀kọ̀ ati apata Dafidi, tí wọ́n kó pamọ́ sinu ilé OLUWA. Àwọn ọmọ ogun sì dúró pẹlu ohun ìjà lọ́wọ́ wọn láti ìhà gúsù ilé náà títí dé ìhà àríwá rẹ̀, wọ́n yí pẹpẹ ati ilé náà ká. Lẹ́yìn náà ni ó mú Joaṣi, ọmọ ọba jáde síta, ó fi adé ọba dé e lórí, ó sì fún un ní ìwé òfin. Lẹ́yìn náà ni ó da òróró sí i lórí láti fi jọba. Àwọn eniyan pàtẹ́wọ́, wọ́n sì kígbe pé, “Kabiyesi, kí ẹ̀mí ọba ó gùn!” Nígbà tí Atalaya gbọ́ ariwo àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin ati ti àwọn eniyan, ó jáde lọ sí ilé OLUWA níbi tí àwọn eniyan péjọ sí. Nígbà tí ó wo ọ̀kánkán, ó wò, ó rí ọba náà tí ó dúró ní ẹ̀bá òpó, ní ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA gẹ́gẹ́ bí àṣà, ó sì rí i tí àwọn olórí ogun ati àwọn afunfèrè yí i ká, tí àwọn eniyan sì ń fi ayọ̀ pariwo, tí wọ́n sì ń fọn fèrè. Atalaya fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn, ó sì kígbe pé, “Ọ̀tẹ̀ nìyí! Ọ̀tẹ̀ nìyí!” Jehoiada kò fẹ́ kí wọ́n pa Atalaya ninu ilé OLUWA, nítorí náà ó pàṣẹ fún àwọn olórí ogun, ó ní, “Ẹ mú un jáde, kí ó wà ní ààrin yín bí ẹ ti ń mú un lọ; ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gbà á là, pípa ni kí ẹ pa á.” Wọ́n bá mú un gba ẹnu ọ̀nà tí àwọn ẹṣin máa ń gbà wọ ààfin, wọ́n sì pa á. Jehoiada alufaa mú kí Joaṣi ọba ati àwọn eniyan dá majẹmu pẹlu OLUWA pé àwọn yóo jẹ́ tirẹ̀; ó sì tún mú kí àwọn eniyan náà bá ọba dá majẹmu. Lẹ́yìn náà, àwọn eniyan lọ sí ilé oriṣa Baali, wọ́n wó o, wọ́n sì wó àwọn pẹpẹ rẹ̀ ati àwọn ère rẹ̀ lulẹ̀. Wọ́n pa Matani, alufaa Baali, níwájú àwọn pẹpẹ náà. Jehoiada sì fi àwọn olùṣọ́ tí wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́ sí ìtọ́jú ilé OLUWA. Òun ati àwọn olórí ogun ati àwọn tí wọ́n ń ṣọ́ ọba ati àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin sin ọba láti ilé OLUWA lọ sí ààfin. Ọba gba ẹnu ọ̀nà àwọn olùṣọ́ wọlé, ó sì jókòó lórí ìtẹ́. Gbogbo àwọn eniyan kún fún ayọ̀, gbogbo ìlú sì ní alaafia lẹ́yìn tí wọ́n ti fi idà pa Atalaya ní ààfin. Ọmọ ọdún meje ni Joaṣi nígbà tí ó jọba. Ní ọdún keje tí Jehu jọba ní Israẹli ni Joaṣi jọba ní ilẹ̀ Juda, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ogoji ọdún. Sibaya tí ó wá láti ìlú Beeriṣeba ni ìyá rẹ̀. Ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ ó ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA nítorí pé Jehoiada alufaa ń tọ́ ọ sọ́nà. Ṣugbọn kò ba àwọn pẹpẹ ìrúbọ jẹ́, àwọn eniyan ń rú ẹbọ níbẹ̀, wọ́n sì ń jó turari. Joaṣi pàṣẹ fún àwọn alufaa pé kí wọ́n máa kó àwọn owó ohun mímọ́ tí wọ́n mú wá sí ilé OLUWA pamọ́: ati gbogbo owó tí àwọn eniyan san fún ẹbọ ìgbà gbogbo ati èyí tí wọ́n mú wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àtinúwá. Alufaa kọ̀ọ̀kan ni yóo máa tọ́jú owó tí wọ́n bá mú wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, yóo sì lo owó náà láti máa tún ilé OLUWA ṣe bí ó ti fẹ́. Àwọn alufaa náà kò tún nǹkankan ṣe ninu ilé OLUWA títí tí ó fi di ọdún kẹtalelogun tí Joaṣi ti jọba. Nítorí náà, ó pe Jehoiada ati àwọn alufaa yòókù, ó bèèrè pé, “Kí ló dé tí ẹ kò fi tún ilé OLUWA ṣe? Láti ìsinsìnyìí lọ, ẹ gbọdọ̀ máa kó owó tí ẹ bá gbà sílẹ̀ fún àtúnṣe ilé OLUWA.” Àwọn alufaa náà gba ohun tí ọba sọ, wọ́n sì gbà pé àwọn kò ní máa gba owó lọ́wọ́ àwọn eniyan mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní tún ilé OLUWA ṣe fúnra wọn. Nígbà náà ni Jehoiada gbé àpótí kan, ó lu ihò sí orí rẹ̀, ó gbé e sí ẹ̀bá pẹpẹ ìrúbọ ní ọwọ́ ọ̀tún tí eniyan bá wọ ilé OLUWA. Gbogbo àwọn alufaa tí wọ́n bá ṣiṣẹ́ ninu ilé OLUWA a sì máa kó owó tí àwọn eniyan bá mú wá sinu rẹ̀. Nígbà tí owó bá pọ̀ ninu àpótí náà, akọ̀wé ọba ati olórí Alufaa yóo ka owó náà, wọn yóo sì dì í sinu àpò. Lẹ́yìn tí wọ́n bá wọn owó náà, wọn yóo gbé àpò owó náà fún àwọn tí wọn ń ṣe àkóso ilé OLUWA. Àwọn ni wọn yóo san owó fún àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà ati àwọn tí wọn ń kọ́lé; ati fún àwọn ọ̀mọ̀lé, ati àwọn agbẹ́kùúta. Ninu rẹ̀, wọn yóo ra igi ati òkúta tí wọn yóo lò fún àtúnṣe náà ati láti san owó gbogbo ohun tí wọ́n nílò fún àtúnṣe ilé OLUWA. Wọn kò lò lára owó náà láti fi ra agbada fadaka, abọ́, fèrè, tabi àwọn ohun èlò wúrà tabi ti fadaka sí ilé OLUWA, ṣugbọn wọn ń lò ó láti fi san owó fún àwọn òṣìṣẹ́ ati láti ra àwọn ohun èlò fún àtúnṣe ilé OLUWA. Wọn kò sì bèèrè àkọsílẹ̀ iye tí àwọn tí wọn ń ṣàkóso iṣẹ́ náà ná nítorí pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́. Ṣugbọn wọn kò da owó ìtanràn ati owó ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pọ̀ mọ́ owó fún àtúnṣe ilé OLUWA, nítorí pé àwọn alufaa ni wọ́n ni owó ìtanràn ati ti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Ní àkókò náà, Hasaeli, ọba Siria gbógun ti ìlú Gati, ó sì ṣẹgun rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó dojú kọ Jerusalẹmu, Joaṣi, ọba Juda, kó gbogbo àwọn ẹ̀bùn mímọ́ tí Jehoṣafati ati Jehoramu ati Ahasaya, àwọn baba ńlá rẹ̀ tí wọ́n ti jọba ṣáájú rẹ̀ yà sọ́tọ̀ fún OLUWA, ati èyí tí òun pàápàá ti yà sọ́tọ̀ ati gbogbo wúrà tí ó wà ninu àwọn ilé ìṣúra ilé OLUWA ati èyí tí ó wà ní ààfin, ó fi wọ́n ranṣẹ sí Hasaeli, ọba Siria. Hasaeli bá kó ogun rẹ̀ kúrò ní Jerusalẹmu. Gbogbo nǹkan yòókù tí Joaṣi ọba ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. Àwọn olórí ogun Joaṣi ọba dìtẹ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì pa á ní ilẹ̀ Milo ní ọ̀nà tí ó lọ sí Sila. Josakari, ọmọ Ṣimeati ati Jehosabadi, ọmọ Ṣomeri, àwọn olórí ogun, ni wọ́n pa á. Wọ́n sì sin ín sí ibojì àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Amasaya ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Ní ọdún kẹtalelogun tí Joaṣi, ọmọ Ahasaya, jọba ní Juda ni Jehoahasi, ọmọ Jehu, jọba lórí Israẹli ní Samaria, ó jọba fún ọdún mẹtadinlogun. Ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu, ọmọ Nebati, tí ó mú Israẹli ṣẹ̀, kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ náà sílẹ̀. OLUWA bínú sí Israẹli, ó sì jẹ́ kí Hasaeli, ọba Siria, ati Benhadadi ọmọ rẹ̀ ṣẹgun Israẹli ní ọpọlọpọ ìgbà. Nígbà tí Jehoahasi gbadura sí OLUWA, tí OLUWA sì rí ìyà tí Hasaeli fi ń jẹ àwọn eniyan Israẹli, ó gbọ́ adura rẹ̀. (Nítorí náà, OLUWA rán olùgbàlà kan sí Israẹli láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Siria, ọkàn àwọn eniyan Israẹli sì balẹ̀ bíi ti ìgbà àtijọ́. Sibẹsibẹ wọn kò yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ tí Jeroboamu ti mú Israẹli dá. Wọ́n sì tún ń dá ẹ̀ṣẹ̀ kan náà, ère oriṣa Aṣera sì wà ní Samaria.) Jehoahasi kò ní àwọn ọmọ ogun mọ́ àfi aadọta ẹlẹ́ṣin, ati kẹ̀kẹ́ ogun mẹ́wàá ati ẹgbaarun (10,000) àwọn ọmọ ogun tí wọn ń fi ẹsẹ̀ rìn. Ọba Siria ti pa gbogbo wọn run, ó lọ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bíi erùpẹ̀. Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoahasi ṣe ati agbára rẹ̀ ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. Ó kú, wọ́n sì sin òkú rẹ̀ sí Samaria. Jehoaṣi ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Ní ọdún kẹtadinlogoji tí Joaṣi jọba ní Juda ni Jehoaṣi, ọmọ Jehoahasi, jọba lórí Israẹli ní Samaria. Ó sì wà lórí oyè fún ọdún mẹrindinlogun. Òun náà ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹni tí ó mú Israẹli ṣẹ̀. Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoaṣi ṣe ati ìwà akọni rẹ̀ ninu ogun tí ó bá Amasaya, ọba Juda, jà ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. Jehoaṣi kú, wọ́n sì sin ín sinu ibojì àwọn ọba Israẹli ní Samaria. Jeroboamu ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Nígbà tí wolii Eliṣa wà ninu àìsàn tí ó le, tí ó sì ń kú lọ, Jehoaṣi, ọba Israẹli lọ bẹ̀ ẹ́ wò, nígbà tí ó rí Eliṣa, ó sọkún, ó sì ń kígbe pé, “Baba mi, baba mi! Ìwọ tí o jẹ́ alátìlẹyìn pataki fún Israẹli!” Eliṣa bá sọ fún un pé kí ó mú ọrun ati ọfà, ó sì mú wọn. Eliṣa sọ fún un pé kí ó múra láti ta ọfà náà, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. Eliṣa gbé ọwọ́ lé ọwọ́ ọba, ó ní kí ọba ṣí fèrèsé, kí ó kọjú sí ìhà ìlà oòrùn, ọba sì ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà, Eliṣa pàṣẹ fún un pé kí ó ta ọfà náà. Bí ọba ti ta ọfà ni Eliṣa ń wí pé, “Ọfà ìṣẹ́gun OLUWA, ọfà ìṣẹ́gun lórí Siria! Nítorí pé o óo bá àwọn Siria jagun ní Afeki títí tí o óo fi ṣẹgun wọn.” Eliṣa tún ní kí ọba máa ta àwọn ọfà yòókù sílẹ̀. Nígbà tí ó ta á lẹẹmẹta, ó dáwọ́ dúró. Èyí bí Eliṣa ninu, ó sì sọ fún ọba pé, “Bí ó bá jẹ́ pé o ta ọfà náà nígbà marun-un tabi mẹfa ni, ò bá ṣẹgun Siria patapata, ṣugbọn báyìí, ìgbà mẹta ni o óo ṣẹgun wọn.” Eliṣa kú, wọ́n sì sin òkú rẹ̀. Ní ọdọọdún ni àwọn ọmọ ogun Moabu máa ń gbógun ti ilẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli. Ní ìgbà kan, bí wọ́n ti fẹ́ máa sìnkú ọkunrin kan, wọ́n rí i tí àwọn ọmọ ogun Moabu ń bọ̀, wọ́n bá ju òkú náà sinu ibojì Eliṣa. Bí ọkunrin náà ti fi ara kan egungun Eliṣa, ó sọjí, ó sì dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀. Hasaeli ọba Siria kò fi àwọn ọmọ Israẹli lọ́kàn balẹ̀ ní gbogbo àkókò ìjọba Jehoahasi. Ṣugbọn OLUWA ṣàánú fún wọn, ó sì yipada sí wọn nítorí majẹmu rẹ̀ pẹlu Abrahamu, ati Isaaki ati Jakọbu; kò sì gbàgbé àwọn eniyan rẹ̀. Nígbà tí Hasaeli Ọba kú, Benhadadi ọmọ rẹ̀ jọba lẹ́yìn rẹ̀. Jehoaṣi ọba, ọmọ Jehoahasi, ṣẹgun Benhadadi ní ìgbà mẹta, ó sì gba àwọn ìlú tí wọ́n ti gbà ní ìgbà ayé Jehoahasi, baba rẹ̀ pada. Ní ọdún keji tí Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi jọba ní Israẹli ni Amasaya ọmọ Joaṣi jọba ní Juda. Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mọkandinlọgbọn ní Jerusalẹmu. Jehoadini, ará Jerusalẹmu, ni ìyá rẹ̀. Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA, ṣugbọn kò dàbí ti Dafidi baba ńlá rẹ̀; ohun gbogbo tí Joaṣi baba rẹ̀ ṣe ni òun náà ṣe. Ṣugbọn kò pa àwọn pẹpẹ oriṣa run; àwọn eniyan ṣì ń rú ẹbọ níbẹ̀, wọ́n sì ń sun turari. Nígbà tí ìjọba rẹ̀ fìdí múlẹ̀ tán, ó pa àwọn olórí ogun tí wọ́n pa baba rẹ̀. Ṣugbọn kò pa àwọn ọmọ wọn nítorí pé òfin Mose pa á láṣẹ pé, “A kò gbọdọ̀ pa baba nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọmọ, bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọdọ̀ pa ọmọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ baba. Olukuluku ni yóo kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.” Amasaya pa ẹgbaarun (10,000) ninu àwọn ọmọ ogun Edomu ní Àfonífojì Iyọ̀. Ó ṣẹgun Sela, ó sì yí orúkọ rẹ̀ pada sí Jokiteeli, orúkọ yìí ni ìlú náà ń jẹ́ títí di òní yìí. Lẹ́yìn náà, Amasaya ranṣẹ sí Jehoaṣi, ọmọ Jehoahasi, ọmọ Jehu, ọba Israẹli, láti pè é níjà sí ogun. Ṣugbọn Jehoaṣi ọba ranṣẹ pada pẹlu òwe yìí: Ó ní, “Ní ìgbà kan ìtàkùn ẹlẹ́gùn-ún kan tí ó wà ní Lẹbanoni ranṣẹ sí igi kedari ní Lẹbanoni pé, ‘Fi ọmọbinrin rẹ fún ọmọkunrin mi ní aya.’ Ṣugbọn ẹranko burúkú kan tí ó wà ní Lẹbanoni ń kọjá lọ, ó sì tẹ ẹ̀gún náà mọ́lẹ̀. Nisinsinyii, ìwọ Amasaya, nítorí pé o ti ṣẹgun Edomu, ọkàn rẹ kún fún ìgbéraga. Jẹ́ kí ògo rẹ yìí tẹ́ ọ lọ́rùn, kí ló dé tí o fi fẹ́ dá ìjàngbọ̀n sílẹ̀ sí ìparun ara rẹ ati ti Juda?” Ṣugbọn Amasaya kọ̀ kò gbọ́, nítorí náà, Jehoaṣi ọba Israẹli kó ogun lọ pàdé Amasaya ọba Juda ní Beti Ṣemeṣi tí ó wà ní Juda. Israẹli ṣẹgun Juda, gbogbo àwọn ọmọ ogun Juda sì pada sí ilé wọn. Ọwọ́ Jehoaṣi tẹ Amasaya, lẹ́yìn náà, ó lọ sí Jerusalẹmu, ó wó odi Jerusalẹmu lulẹ̀ láti Ẹnubodè Efuraimu títí dé Ẹnubodè Igun, gbogbo rẹ̀ jẹ́ irinwo igbọnwọ (400 mita). Ó kó gbogbo fadaka ati wúrà tí ó rí ati gbogbo àwọn ohun èlò ilé OLUWA ati gbogbo ohun tí ó níye lórí ní ààfin, ó sì pada sí Samaria. Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoaṣi ṣe, ati ìwà akọni rẹ̀ ninu ogun tí ó bá Amasaya jà, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. Jehoaṣi kú, wọ́n sin òkú rẹ̀ sinu ibojì àwọn ọba ní Samaria. Jeroboamu ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Amasaya ọba, ọmọ Joaṣi gbé ọdún mẹẹdogun lẹ́yìn ikú Jehoaṣi ọba Israẹli. Gbogbo nǹkan yòókù tí Amasaya ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. Wọ́n dìtẹ̀ mọ́ Amasaya Ọba ní Jerusalẹmu, ó sì sá lọ sí Lakiṣi. Ṣugbọn wọ́n rán eniyan lọ bá a níbẹ̀, wọ́n sì pa á. Wọ́n gbé òkú rẹ̀ sórí ẹṣin wá sí Jerusalẹmu, wọ́n sì sin ín sinu ibojì àwọn ọba, ní ìlú Dafidi. Àwọn eniyan Juda sì fi Asaraya, ọmọ rẹ̀, jọba. Ẹni ọdún mẹrindinlogun ni, nígbà tí ó jọba. Asaraya tún ìlú Elati kọ́, ó sì dá a pada fún Juda lẹ́yìn ikú baba rẹ̀. Ní ọdún kẹẹdogun tí Amasaya ọmọ Joaṣi jọba ní Juda ni Jeroboamu, ọmọ Jehoaṣi, ọba Israẹli jọba ní Samaria, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mọkanlelogoji. Ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA; ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu, ọmọ Nebati, tí ó mú Israẹli dẹ́ṣẹ̀. Ó gba gbogbo ilẹ̀ Israẹli pada láti ẹnubodè Hamati títí dé Òkun Araba, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí OLUWA Ọlọrun Israẹli sọ láti ẹnu wolii rẹ̀, Jona, ọmọ Amitai, ará Gati Heferi. OLUWA rí i pé ìpọ́njú àwọn ọmọ Israẹli pọ̀, kò sì sí ẹni tí ìpọ́njú náà kò kàn, ati ẹrú ati ọmọ, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni OLUWA kò tíì sọ pé òun óo pa gbogbo Israẹli run, nítorí náà, ó ṣẹgun fún wọn láti ọwọ́ Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi. Gbogbo nǹkan yòókù tí Jeroboamu ṣe, ìwà akọni rẹ̀ lójú ogun ati bí ó ti gba Damasku ati Hamati, tí wọ́n jẹ́ ti Juda tẹ́lẹ̀ rí, fún Israẹli, gbogbo rẹ̀ ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. Jeroboamu kú, wọ́n sin òkú rẹ̀ sinu ibojì àwọn ọba, Sakaraya, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Ní ọdún kẹtadinlọgbọn tí Jeroboamu jọba ní Israẹli ni Asaraya ọmọ Amasaya, jọba ní Juda. Ẹni ọdún mẹrindinlogun ni nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mejilelaadọta. Jekolaya ará Jerusalẹmu ni ìyá rẹ̀. Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA nítorí pé ó tẹ̀lé ọ̀nà Amasaya, baba rẹ̀. Ṣugbọn kò pa àwọn pẹpẹ oriṣa run, àwọn eniyan ṣì ń rúbọ; wọ́n sì ń sun turari níbẹ̀. OLUWA sọ Asaraya ọba di adẹ́tẹ̀, ó sì wà bẹ́ẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀, ó ń dá gbé. Jotamu ọmọ rẹ̀ sì ń ṣàkóso ìjọba nípò rẹ̀. Gbogbo nǹkan yòókù tí Asaraya ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. Ó kú, wọ́n sì sin ín sinu ibojì àwọn ọba ní ìlú Dafidi, Jotamu, ọmọ rẹ̀, sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Ní ọdún kejidinlogoji tí Asaraya jọba ní Juda ni Sakaraya ọmọ Jeroboamu jọba lórí Israẹli, ní Samaria, ó sì wà lórí oyè fún oṣù mẹfa. Ó ṣe ohun burúkú níwájú OLUWA gẹ́gẹ́ bí àwọn baba rẹ̀ ti ṣe. Ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu; ọmọ Nebati, tí ó mú Israẹli dẹ́ṣẹ̀. Ṣalumu ọmọ Jabeṣi dìtẹ̀ mọ́ ọn, ó pa á ní Ibileamu, ó sì jọba dípò rẹ̀. Gbogbo nǹkan yòókù tí Sakaraya ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. OLUWA ṣèlérí fún Jehu pé, “Àwọn ọmọ rẹ títí dé ìran kẹrin yóo jọba ní Israẹli.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ní ọdún kọkandinlogoji tí Asaraya ti jọba ní Juda ni Ṣalumu, ọmọ Jabeṣi, jọba lórí Israẹli, ní Samaria, ó wà lórí oyè fún oṣù kan. Menahemu ọmọ Gadi lọ sí Samaria láti Tirisa, ó pa Ṣalumu ọba, ó sì jọba dípò rẹ̀. Gbogbo nǹkan yòókù tí Ṣalumu ṣe, ati ìwà ọ̀tẹ̀ tí ó hù ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. Ní àkókò náà Menahemu pa ìlú Tapua run, ati àwọn ìlú tí wọ́n yí i ká láti Tirisa, nítorí pé wọn kò ṣí ìlẹ̀kùn ìlú náà fún un, ó sì la inú gbogbo àwọn aboyún tí wọ́n wà níbẹ̀. Ní ọdún kọkandinlogoji tí Asaraya jọba ní Juda, ni Menahemu, ọmọ Gadi, jọba lórí Israẹli ní Samaria, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mẹ́wàá. Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA títí di ọjọ́ ikú rẹ̀, nítorí pé ó tẹ̀lé ọ̀nà Jeroboamu ọba, ọmọ Nebati, tí ó mú Israẹli dẹ́ṣẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. Pulu, tí à ń pè ní Tigilati Pileseri, ọba Asiria, gbógun ti ilẹ̀ Israẹli; kí ó baà lè ran Menahemu lọ́wọ́ láti fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀, Menahemu fún un ní ẹgbẹrun (1,000) talẹnti owó fadaka. Ọwọ́ àwọn ọlọ́rọ̀ Israẹli ni ọba ti gba owó náà, ó pàṣẹ pé kí olukuluku dá aadọta ṣekeli owó fadaka. Ọba Asiria bá pada sí ilẹ̀ rẹ̀. Gbogbo nǹkan yòókù tí Menahemu ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. Ó kú, wọ́n sì sin òkú rẹ̀, Pekahaya, ọmọ rẹ̀, sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Nígbà tí ó di aadọta ọdún tí Asaraya jọba ní Juda, ni Pekahaya, ọmọ Menahemu jọba lórí Israẹli, ní Samaria, ó sì wà lórí oyè fún ọdún meji. Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA; ó sì tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu, ọmọ Nebati, tí ó mú Israẹli dẹ́ṣẹ̀. Peka, ọmọ Remalaya, olórí ogun rẹ̀, pẹlu aadọta ọmọ ogun Gileadi dìtẹ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì pa á ní Samaria, ninu ilé tí a mọ odi tí ó lágbára yíká, tí ó wà ninu ààfin rẹ̀, Peka sì jọba dípò rẹ̀. Gbogbo nǹkan yòókù tí Pekahaya ṣe, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. Ní ọdún kejilelaadọta tí Asaraya jọba ní Juda, ni Peka, ọmọ Remalaya, jọba lórí Israẹli ní Samaria, ó sì wà lórí oyè fún ogún ọdún. Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu, ọmọ Nebati, tí ó mú Israẹli dẹ́ṣẹ̀. Ní àkókò tí Peka jọba Israẹli ni Tigilati Pileseri, ọba Asiria, gba ìlú Ijoni, Abeli Beti Maaka, Janoa, Kedeṣi, Hasori, ati ilẹ̀ Gileadi, Galili ati gbogbo ilẹ̀ Nafutali, ó sì kó àwọn eniyan ibẹ̀ lẹ́rú lọ sí Asiria. Ní ogún ọdún tí Jotamu, ọmọ Usaya jọba Juda, ni Hoṣea, ọmọ Ela, dìtẹ̀ mọ́ Peka ọba, ó pa á, ó sì jọba dípò rẹ̀. Gbogbo nǹkan yòókù tí Peka ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. Ní ọdún keji tí Peka ọmọ Remalaya, jọba ní Israẹli, ni Jotamu, ọmọ Usaya, jọba ní Juda. Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni nígbà tí ó jọba, ó sì jọba fún ọdún mẹrindinlogun ní Jerusalẹmu. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Jeruṣa, ọmọ Sadoku. Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA nítorí pé ó tẹ̀ sí ọ̀nà Usaya, baba rẹ̀. Ṣugbọn kò pa àwọn pẹpẹ ìrúbọ run, àwọn eniyan ṣì ń rú ẹbọ, wọ́n sì ń sun turari níbẹ̀. Òun ni ó kọ́ ẹnu ọ̀nà apá ìhà àríwá ilé OLUWA. Gbogbo nǹkan yòókù tí Jotamu ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. Ní àkókò tí ó jọba ni OLUWA bẹ̀rẹ̀ sí rán Resini, ọba Siria, ati Peka, ọmọ Remalaya, tí í ṣe ọba Israẹli, láti gbógun ti Juda. Jotamu kú, wọ́n sin ín sinu ibojì àwọn ọba ní ìlú Dafidi; Ahasi ọmọ rẹ̀, sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Ní ọdún kẹtadinlogun tí Peka, ọmọ Remalaya, jọba ní Israẹli, ni Ahasi, ọmọ Jotamu, jọba ní Juda. Ẹni ogún ọdún ni Ahasi nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mẹrindinlogun. Kò tẹ̀lé àpẹẹrẹ rere Dafidi baba ńlá rẹ̀, ṣugbọn ó ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀, nípa títẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọba Israẹli. Òun náà tilẹ̀ fi ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ sísun sí oriṣa gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè oníwà burúkú tí OLUWA lé kúrò lórí ilẹ̀ náà fún àwọn ọmọ Israẹli. Ní gbogbo ibi gíga, ati àwọn orí òkè ati abẹ́ gbogbo igi ni Ahasi tií máa rúbọ, tíí sìí sun turari. Resini, ọba Siria, ati Peka, ọba Israẹli, gbógun ti Jerusalẹmu, wọ́n sì dó ti Ahasi, ṣugbọn wọn kò lè ṣẹgun rẹ̀. Ní àkókò kan náà ni ọba Edomu gba Elati pada, ó sì lé àwọn ará Juda tí wọn ń gbé ibẹ̀, àwọn ará Edomu sì ń gbé ibẹ̀ títí di òní olónìí. Ahasi ranṣẹ lọ bá Tigilati Pileseri, ọba Asiria, ó ní, “Iranṣẹ ati ọmọ rẹ ni mo jẹ́, nítorí náà, jọ̀wọ́ wá gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọba Siria ati ti Israẹli tí wọ́n gbógun tì mí.” Ahasi kó fadaka ati wúrà tí ó wà ninu ilé OLUWA, ati tinú àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ní ààfin jọ, ó kó o ranṣẹ sí ọba Asiria. Ọba Asiria gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀, ó sì gbógun ti Damasku, ó ṣẹgun rẹ̀, ó pa Resini ọba, ó sì kó gbogbo àwọn eniyan ìlú náà lẹ́rú lọ sí Kiri. Nígbà tí Ahasi lọ pàdé Tigilati Pileseri ọba, ní Damasku, ó rí pẹpẹ ìrúbọ kan níbẹ̀, ó sì ranṣẹ sí Uraya alufaa pé kí ó mọ irú rẹ̀ gan-an láìsí ìyàtọ̀ kankan. Ki Ahasi tó dé, Uraya bá mọ irú pẹpẹ ìrúbọ náà, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tí Ahasi rán sí i láti Damasku. Nígbà tí Ahasi pada dé, o rí i pé Uraya ti mọ pẹpẹ ìrúbọ náà; ó lọ sí ìdí rẹ̀, ó sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ lórí rẹ̀. Ó rú ẹbọ ohun mímu, ó sì da ẹ̀jẹ̀ ẹbọ alaafia rẹ̀ sí ara rẹ̀. Pẹpẹ idẹ tí a ti yà sọ́tọ̀ fún OLUWA wà ní ààrin pẹpẹ tirẹ̀ ati ilé OLUWA. Nítorí náà, Ahasi gbé pẹpẹ idẹ náà sí apá òkè pẹpẹ tirẹ̀. Lẹ́yìn náà ó pàṣẹ fún Uraya alufaa, ó ní, “Máa lo pẹpẹ ìrúbọ tí ó tóbi yìí fún ẹbọ sísun àárọ̀ ati ẹbọ ohun jíjẹ ìrọ̀lẹ́, ati fún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ti ọba, ati fún ẹbọ ohun jíjẹ ati ti ohun mímu ti àwọn eniyan. Kí o sì máa da ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn ẹran tí wọ́n bá pa fún ìrúbọ sí orí rẹ̀. Ṣugbọn gbé pẹpẹ ìrúbọ idẹ tọ̀hún sọ́tọ̀ fún mi kí n lè máa lò ó láti wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ OLUWA.” Uraya sì ṣe bí Ahasi ọba ti pa á láṣẹ fún un. Ahasi gé àwọn ẹsẹ̀ idẹ ti agbada ńlá, ó gbé agbada náà kúrò. Ó tún gbé agbada omi ńlá tí a fi idẹ ṣe, tí wọ́n gbé ka ẹ̀yìn àwọn akọ mààlúù idẹ mejila, ó sì gbé e lé orí ìpìlẹ̀ tí a fi òkúta ṣe. Nítorí pé Ahasi fẹ́ tẹ́ ọba Asiria lọ́rùn, ó gbé pátákó tí wọ́n tẹ́ fún ìtẹ́ ọba kúrò, ó sì sọ ibẹ̀ dí ẹnu ọ̀nà tí ọba ń gbà wọ ilé OLUWA. Gbogbo nǹkan yòókù tí Ahasi ọba ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. Ahasi kú, wọn sì sin òkú rẹ̀ sinu ibojì àwọn ọba ní ìlú Dafidi, Hesekaya, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Ní ọdún kejila tí Ahasi jọba ní Juda, ni Hoṣea ọmọ Ela jọba lórí Israẹli, ní Samaria, ó sì jọba fún ọdún mẹsan-an. Ó ṣe nǹkan tí ó burú lójú OLUWA, ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kò tó ti àwọn ọba tí wọ́n jẹ ṣáájú rẹ̀. Ṣalimaneseri Ọba Asiria gbógun tì í; Hoṣea bá jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún un, ó sì ń san ìṣákọ́lẹ̀ fún un ní ọdọọdún. Ṣugbọn ní ọdún kan, Hoṣea ranṣẹ sí So, ọba Ijipti pé, kí ó ran òun lọ́wọ́, kò sì san ìṣákọ́lẹ̀ fún ọba Asiria mọ́. Nígbà tí Ṣalimaneseri gbọ́, ó pàṣẹ pé kí wọ́n ju Hoṣea sinu ọgbà ẹ̀wọ̀n. Lẹ́yìn náà, Ṣalimaneseri, ọba Asiria, gbógun ti ilẹ̀ Israẹli, ó dó ti Samaria fún ọdún mẹta. Ní ọdún kẹsan-an tí Hoṣea jọba, ọba Asiria ṣẹgun Samaria, ó sì kó àwọn ọmọ Israẹli ní ìgbèkùn lọ sí Asiria. Ó kó wọn sí ìlú Hala ati sí etí odò Habori tí ó wà ní agbègbè Gosani, ati sí àwọn ìlú Media. Ogun kó Samaria nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun wọn ó gbà wọ́n lọ́wọ́ ọba Farao, tí ó sì kó wọn jáde kúrò ní Ijipti. Wọ́n ti bọ oriṣa, wọ́n sì tẹ̀lé ìwà àwọn eniyan tí OLUWA lé jáde kúrò fún wọn, ati àwọn àṣàkaṣà tí àwọn ọba Israẹli kó wá. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe oríṣìíríṣìí nǹkan níkọ̀kọ̀, tí OLUWA Ọlọrun wọn kò fẹ́. Wọ́n kọ́ àwọn pẹpẹ ìrúbọ sinu àwọn ìlú wọn: wọ́n kọ́ sinu ilé ìṣọ́, títí kan àwọn ìlú olódi. Wọ́n gbé àwọn òpó tí a fi òkúta ṣe ati àwọn ère Aṣerimu sí orí àwọn òkè ati sí abẹ́ àwọn igi tí wọ́n ní ìbòòji. Wọ́n ń sun turari ní gbogbo orí òkè, gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwọn tí OLUWA lé jáde kúrò ní ilẹ̀ náà. Wọ́n mú kí ibinu OLUWA ru pẹlu ìwà burúkú wọn, wọ́n sì lòdì sí àṣẹ tí OLUWA pa fún wọn pé wọn kó gbọdọ̀ bọ oriṣa. Sibẹ, OLUWA ń rán àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati àwọn wolii rẹ̀ kí wọ́n máa kìlọ̀ fún Israẹli ati Juda pé, “Ẹ kọ ọ̀nà burúkú yín sílẹ̀ kí ẹ sì pa òfin ati ìlànà mi, tí mo fún àwọn baba ńlá yín mọ́; àní àwọn tí mo fun yín nípasẹ̀ àwọn wolii, iranṣẹ mi.” Ṣugbọn wọn kò gbọ́, wọ́n jẹ́ ọlọ́kàn líle bí àwọn baba ńlá wọn, tí wọn kò gba OLUWA Ọlọrun wọn gbọ́. Wọ́n kọ ìlànà rẹ̀, wọn kò pa majẹmu tí ó bá àwọn baba ńlá wọn dá mọ́, wọn kò sì fetí sí àwọn ìkìlọ̀ rẹ̀. Wọ́n ń sin oriṣa lásánlàsàn, àwọn pàápàá sì di eniyan lásán. Wọ́n tẹ̀ sí ìwà àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká; wọ́n kọ òfin tí OLUWA ṣe fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọ̀nà wọn. Wọ́n rú gbogbo òfin OLUWA Ọlọrun wọn; wọ́n yá ère ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù meji, wọ́n ń sìn wọ́n. Wọ́n gbẹ́ ère oriṣa Aṣera, wọ́n sì ń bọ àwọn ohun tí ó wà lójú ọ̀run ati oriṣa Baali. Wọ́n fi àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin wọn rú ẹbọ sísun sí oriṣa, wọ́n ń ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ati àwọn alásọtẹ́lẹ̀, wọ́n sì fi ara wọn jì láti ṣe nǹkan tí ó burú lójú OLUWA, wọ́n sì fi bẹ́ẹ̀ rú ibinu rẹ̀ sókè. Nítorí náà, OLUWA bínú sí àwọn ọmọ Israẹli, ó sì run wọ́n kúrò níwájú rẹ̀, ṣugbọn ó fi Juda nìkan sílẹ̀. Sibẹ, àwọn ará Juda kò pa òfin OLUWA Ọlọrun wọn mọ́, wọ́n tẹ̀lé ìwà tí àwọn ọmọ Israẹli ń hù. OLUWA bá kọ gbogbo àwọn ìran Israẹli sílẹ̀, ó jẹ wọ́n níyà, ó sì fi wọ́n lé àwọn apanirun lọ́wọ́ títí wọ́n fi pa wọn run níwájú rẹ̀. Lẹ́yìn tí OLUWA ti fi ìyapa sí ààrin Israẹli ati ìdílé Dafidi, Israẹli fi Jeroboamu ọmọ Nebati jọba. Jeroboamu mú kí wọ́n kọ OLUWA sílẹ̀, ó sì mú kí wọ́n dẹ́ṣẹ̀ ńlá. Àwọn ọmọ Israẹli ń tẹ̀lé gbogbo ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu, wọn kò sì yipada kúrò ninu wọn, títí tí OLUWA fi run wọ́n kúrò níwájú rẹ̀, bí ó ti kìlọ̀ fún wọn láti ẹnu àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Asiria ṣe kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli lọ sí ìgbèkùn ní ilẹ̀ Asiria, níbi tí wọ́n wà títí di òní olónìí. Ọba Asiria kó àwọn eniyan láti Babiloni, Kuta, Afa, Hamati ati Sefafaimu, ó kó wọn dà sinu àwọn ìlú Samaria dípò àwọn ọmọ Israẹli tí ó kó lọ. Wọ́n gba ilẹ̀ Samaria, wọ́n sì ń gbé inú àwọn ìlú rẹ̀. Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ dé ibẹ̀, wọn kò bẹ̀rù OLUWA, nítorí náà OLUWA rán àwọn kinniun sí ààrin wọn, wọ́n sì pa ninu àwọn eniyan tí ọba Asiria kó wá. Wọ́n bá lọ ròyìn fún ọba Asiria pé àwọn eniyan tí ó kó lọ sí ilẹ̀ Samaria kò mọ òfin Ọlọrun ilẹ̀ náà, nítorí náà ni Ọlọrun ṣe rán kinniun tí ó ń pa wọ́n. Ọba bá pàṣẹ, ó ní, “Ẹ dá ọ̀kan ninu àwọn alufaa tí a kó lẹ́rú pada sí Samaria, kí ó lè kọ́ àwọn eniyan náà ní òfin Ọlọrun ilẹ̀ náà.” Nítorí náà, ọ̀kan ninu àwọn alufaa tí wọ́n kó wá láti Samaria pada lọ, ó sì ń gbé Bẹtẹli, níbẹ̀ ni ó ti ń kọ́ àwọn eniyan náà bí wọn yóo ṣe máa sin OLUWA. Ṣugbọn àwọn oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè tí ń gbé Samaria ṣì ń gbẹ́ ère oriṣa wọn, wọ́n fi wọ́n sinu àwọn ilé oriṣa tí àwọn ọmọ Israẹli ti kọ́. Olukuluku wọn ṣe oriṣa tirẹ̀ sí ibi tí ó ń gbé. Àwọn ará Babiloni gbẹ́ ère oriṣa Sukotu Benoti, àwọn ará Kuti gbẹ́ ère oriṣa Negali, àwọn ará Hamati gbẹ́ ère oriṣa Aṣima, àwọn ará Afa gbẹ́ ère oriṣa Nibihasi ati Tataki, àwọn ará Sefafaimu sì ń sun ọmọ wọn ninu iná fún Adirameleki ati Anameleki, àwọn oriṣa wọn. Àwọn eniyan náà bẹ̀rù OLUWA pẹlu, wọ́n sì yan oniruuru eniyan lára wọn, láti máa ṣe alufaa níbi àwọn pẹpẹ oriṣa gíga, láti máa bá wọn rúbọ níbẹ̀. Wọ́n ń sin OLUWA, ṣugbọn wọ́n tún ń bọ àwọn oriṣa tí wọn ń bọ tẹ́lẹ̀ ní orílẹ̀-èdè tí olukuluku wọ́n ti wá. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń ṣe títí di òní olónìí. Wọn kò bẹ̀rù OLUWA, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tẹ̀lé ìlànà rẹ̀, tabi àṣẹ tí ó pa, tabi òfin tí ó ṣe fún àwọn ọmọ Jakọbu, tí ó sọ ní Israẹli. OLUWA bá wọn dá majẹmu, ó sì pàṣẹ fún wọn, pé, wọn kò gbọdọ̀ bọ oriṣa, tabi kí wọ́n júbà wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbọdọ̀ sìn wọ́n tabi kí wọ́n rúbọ sí wọn; ṣugbọn wọ́n gbọdọ̀ bẹ̀rù OLUWA tí ó mú wọn jáde kúrò ní Ijipti pẹlu ọwọ́ agbára ńlá ati ipá. Ó ní kí wọ́n máa tẹríba fún un, kí wọn sì máa rúbọ sí i. Ó ní wọ́n gbọdọ̀ pa àwọn ìlànà, àṣẹ ati òfin tí ó kọ sílẹ̀ fún wọn mọ́. Wọn kò gbọdọ̀ bẹ̀rù àwọn oriṣa, wọn kò sì gbọdọ̀ gbàgbé majẹmu tí òun bá wọn dá. Wọn kò gbọdọ̀ bẹ̀rù àwọn oriṣa, ṣugbọn kí wọn bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun wọn, yóo sì gbà wọ́n lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá wọn. Ṣugbọn àwọn eniyan náà kò gbọ́, wọ́n sì ń tẹ̀lé ìwà àtijọ́ wọn. Àwọn eniyan ilẹ̀ náà sin OLUWA, ṣugbọn wọ́n ń bọ àwọn ère tí wọ́n gbẹ́ pẹlu. Àwọn ọmọ ati àwọn ọmọ ọmọ wọn sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ títí di òní olónìí. Ní ọdún kẹta tí Hoṣea, ọmọ Ela, jọba ní Israẹli ni Hesekaya, ọmọ Ahasi jọba ní Juda. Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni nígbà tí ó jọba, ó sì jọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkandinlọgbọn. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Abi, ọmọ Sakaraya. Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA, nítorí pé ó tẹ̀lé àpẹẹrẹ Dafidi, baba ńlá rẹ̀. Ó wó gbogbo àwọn pẹpẹ oriṣa, ó wó gbogbo àwọn òpó tí wọ́n fi òkúta ṣe, ó sì gé gbogbo àwọn ère oriṣa Aṣera. Ó rún ejò idẹ tí Mose ṣe, tí wọn ń pè ní Nehuṣitani nítorí pé títí di àkókò náà àwọn ọmọ Israẹli a máa sun turari sí i. Hesekaya ní igbagbọ ninu OLUWA Ọlọrun Israẹli. Juda kò sì ní ọba mìíràn tí ó dà bíi rẹ̀, yálà ṣáájú rẹ̀ ni, tabi lẹ́yìn rẹ̀. Ó jẹ́ olóòótọ́ sí OLUWA, kò yapa kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, ṣugbọn ó fi tọkàntọkàn pa àwọn òfin tí OLUWA fún Mose mọ́. OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ó sì ń ṣe àṣeyọrí ninu gbogbo ohun tí ó ń ṣe. Ó gba ara rẹ̀ lọ́wọ́ ọba Asiria, ó di òmìnira, ó kọ̀ kò sìn ín mọ́. Ó ṣẹgun àwọn ará Filistia, títí dé ìlú Gasa ati agbègbè tí ó yí i ká, ati ilé ìṣọ́ wọn, ati ìlú olódi wọn. Ní ọdún kẹrin tíí Hesekaya jọba, tíi ṣe ọdún keje tí Hoṣea, ọmọ Ela, jọba lórí Israẹli, Ṣalimaneseri, ọba Asiria, gbógun ti Samaria, ó sì dó tì í. Nígbà tí ó ti di ọdún kẹta tí ó ti dó ti Samaria, ó ṣẹgun rẹ̀. Èyí jẹ́ ọdún kẹfa tí Hesekaya jọba, ati ọdún kẹsan-an tí Hoṣea jọba. Ọba Asiria kó àwọn ọmọ Israẹli ní ìgbèkùn lọ sí Asiria, ó sì kó wọn sí ìlú Hala ati Habori tí ó wà ní agbègbè odò Gosani ati sí àwọn ìlú àwọn ará Media. Ogun kó Samaria nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli kò pa òfin OLUWA Ọlọrun wọn mọ́, wọ́n si da majẹmu tí OLUWA bá wọn dá. Wọn kò pa àwọn òfin tí OLUWA fún Mose, iranṣẹ rẹ̀ mọ́, wọn kò sì gbọ́ràn. Ní ọdún kẹrinla tí Hesekaya jọba ní Juda, ni Senakeribu, ọba Asiria, gbógun ti àwọn ìlú olódi Juda, ó sì ṣẹgun wọn. Hesekaya ranṣẹ sí Senakeribu, ọba Asiria, tí ó wà ní Lakiṣi nígbà náà, ó ní: “Mo ti ṣẹ̀, jọ̀wọ́ dá ọwọ́ ogun rẹ dúró; n óo sì san ohunkohun tí o bá bèèrè.” Ọba náà sì bèèrè fún ọọdunrun ìwọ̀n talẹnti fadaka ati ọgbọ̀n ìwọ̀n talẹnti wúrà lọ́wọ́ Hesekaya ọba Juda. Hesekaya bá kó gbogbo fadaka tí ó wà ninu ilé OLUWA ati ti inú ilé ìṣúra tí ó wà ní ààfin ranṣẹ sí i. Ó sì ṣí wúrà tí ó wà lára ìlẹ̀kùn ilé OLUWA ati wúrà tí òun tìkararẹ̀ fi bo àwọn òpó ìlẹ̀kùn, ó kó wọn ranṣẹ sí Senakeribu. Ọba Asiria rán àwọn ọ̀gágun rẹ̀: Tatani, Rabusarisi ati Rabuṣake pẹlu ọpọlọpọ ọmọ ogun láti Lakiṣi láti gbógun ti Hesekaya ní Jerusalẹmu. Nígbà tí wọ́n dé Jerusalẹmu wọ́n dúró sí ibi ọ̀nà tí àwọn tí wọn ń hun aṣọ tí ń ṣiṣẹ́, lẹ́bàá kòtò omi tí ń ṣàn wá láti adágún omi tí ó wà ninu ìlú lápá òkè. Nígbà tí wọ́n ké sí Hesekaya ọba, Eliakimu, ọmọ Hilikaya tí ó ń ṣe àkóso ààfin, ati Ṣebina akọ̀wé ọba, ati Joa ọmọ Asafu, tí ń ṣe àkóso ìwé ìrántí ni wọ́n jáde sí wọn. Rabuṣake ní, “Ẹ sọ fún Hesekaya pé, ọba ńlá, ọba ilẹ̀ Asiria ní kí ni ó gbẹ́kẹ̀lé? Ṣé ó rò pé ọ̀rọ̀ lásán lè dípò ọgbọ́n ati agbára ogun ni? Ó ní, ta ni Hesekaya gbẹ́kẹ̀lé tí ó fi ń dìtẹ̀ mọ́ òun? Ṣé Ijipti ni ó gbójú lé pé yóo ran òun lọ́wọ́? Ó ní ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí ẹni tí ó ń fi igi tí kò ní agbára ṣe ọ̀pá ìtilẹ̀. Tí igi náà bá dá, yóo gún un lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ijipti rí sí gbogbo àwọn tí wọ́n bá gbẹ́kẹ̀ wọn lé e. “Ṣugbọn tí ẹ bá sọ fún mi pé ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA Ọlọrun yín, ṣebí àwọn ibi ìrúbọ ati àwọn pẹpẹ Ọlọrun náà ni Hesekaya ti bàjẹ́, tí ó sì sọ fún àwọn ará Juda ati Jerusalẹmu pé, ‘Níwájú pẹpẹ tí ó wà ní Jerusalẹmu nìkan ni kí ẹ ti máa sìn.’ Nisinsinyii, ẹ wá ṣe àdéhùn pẹlu ọba Asiria, oluwa mi. N óo fun yín ní ẹgbaa (2,000) ẹṣin bí ẹ bá lè rí ẹgbaa (2,000) eniyan tí yóo gùn wọ́n. Ẹ kò lè ṣẹgun ẹni tí ó kéré jùlọ ninu àwọn ọ̀gágun ọba Asiria, sibẹ o rò pé àwọn kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin ọba Ijipti yóo ràn ọ́ lọ́wọ́. Ṣé o rò pé lásán ni mo wá láti pa ilẹ̀ yìí run, láìsí ìrànlọ́wọ́ OLUWA? OLUWA fúnra rẹ̀ ni ó sọ fún mi pé kí n wá pa ilẹ̀ yìí run.” Nígbà náà ni Eliakimu, ọmọ Hilikaya ati Ṣebina ati Joa sọ fún Rabuṣake pé, “Jọ̀wọ́, bá àwa iranṣẹ rẹ sọ̀rọ̀ ní èdè Aramaiki nítorí pé a gbọ́. Má sọ èdè Heberu mọ́, nítorí pé àwọn tí wọ́n wà lórí odi ń gbọ́ ohun tí ò ń sọ.” Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Ṣé ẹ rò pé ẹ̀yin ati ọba nìkan ni ọba Asiria rán mi sí ni? Rárá, àwọn tí wọ́n wà lórí odi náà wà lára àwọn tí mò ń bá sọ̀rọ̀. Àwọn náà yóo jẹ ìgbẹ́ ara wọn tí wọn yóo sì mu ìtọ̀ ara wọn bí ẹ̀yin náà.” Nígbà náà ni Rabuṣake kígbe sókè rara ní èdè Heberu tíí ṣe èdè àwọn ará Juda ó ní, “Ẹ gbọ́ ohun tí ọba Asiria ń sọ fun yín; ó ní òun ń kìlọ̀ fun yín pé kí ẹ má jẹ́ kí Hesekaya tàn yín jẹ, kò lè gbà yín sílẹ̀. Ó ní kí ẹ má ṣe jẹ́ kí ó mú ki ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA kí ó máa sọ pé OLUWA yóo gbà yín sílẹ̀, ati pé kò ní jẹ́ kí ogun Asiria kó ìlú yín. Ẹ má ṣe gbọ́ ti Hesekaya; nítorí pé ọba Asiria ní kí ẹ jáde wá kí ẹ bá òun ṣe àdéhùn alaafia; òun yóo gbà yín láàyè láti máa jẹ èso àjàrà ninu ọgbà àjàrà yín. Ẹ óo máa jẹ èso orí igi ọ̀pọ̀tọ́ yín, ẹ óo sì máa mu omi láti inú kànga yín; títí di ìgbà tí òun óo fi ko yín lọ sí ilẹ̀ mìíràn tí yóo dàbí tiyín, ilẹ̀ tí ó kún fún ọkà ati waini, ilẹ̀ tí ó kún fún oúnjẹ ati ọgbà àjàrà, ilẹ̀ tí ó kún fún igi olifi ati oyin, kí ẹ lè wà láàyè, kí ẹ má baà kú. Ẹ má jẹ́ kí Hesekaya tàn yín, kí ẹ máa rò pé OLUWA yóo gbà yín. Ṣé ọlọrun àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn gbà wọ́n lọ́wọ́ ọba Asiria? Níbo ni ọlọrun Hamati ati ti Aripadi wà? Níbo ni àwọn ọlọrun Sefafaimu, ati ti Hena ati ti Ifa wà? Ṣé wọ́n gba Samaria lọ́wọ́ mi? Nígbà wo ni ọ̀kan ninu àwọn ọlọrun orílẹ̀-èdè wọnyi gba orílẹ̀-èdè wọn lọ́wọ́ ọba Asiria rí, tí OLUWA yóo fi gba Jerusalẹmu lọ́wọ́ mi?” Àwọn eniyan náà dákẹ́ jẹ́ẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọba Hesekaya ti pàṣẹ fún wọn, wọn kò sọ ọ̀rọ̀ kankan. Nígbà náà ni Eliakimu, tí ń ṣe àkóso ààfin ati Ṣebina, akọ̀wé ọba, ati Joa, tí ń ṣe àkóso ìwé ìrántí fa aṣọ wọn ya láti fi ìbànújẹ́ wọn hàn, wọ́n sì lọ sọ ohun tí olórí ogun náà wí fun ọba. Nígbà tí Hesekaya ọba gbọ́, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora, ó bá lọ sinu ilé OLUWA. Ó rán Eliakimu ati Ṣebina ati àwọn àgbààgbà alufaa, tí wọ́n fi aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara wọn, lọ sọ́dọ̀ wolii Aisaya ọmọ Amosi. Wọ́n sì jíṣẹ́ Hesekaya ọba fún Aisaya pé, “Ọba sọ pé òní jẹ́ ọjọ́ ìrora, wọ́n ń fi ìyà jẹ wá, a sì wà ninu ìtìjú. A dàbí aboyún tí ó fẹ́ bímọ ṣugbọn tí kò ní agbára tó. Ọba Asiria ti rán Rabuṣake, olórí ogun rẹ̀ kan, láti sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí Ọlọrun alààyè. Kí OLUWA Ọlọrun rẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn yìí, kí ó sì jẹ àwọn tí wọ́n sọ ọ́ níyà. Nítorí náà, gbadura fún àwọn eniyan wa tí wọ́n kù.” Nígbà tí wọ́n jíṣẹ́ ọba fún Aisaya tán, ó ranṣẹ pada ó ní, “Ẹ sọ fún ọ̀gá yín pé OLUWA ní kí ó má jẹ́ kí iṣẹ́ tí ọba Asiria rán sí i pé OLUWA kò lè gbà á dẹ́rùbà á. Ó ní òun óo fi ẹ̀mí kan sinu rẹ̀, tí yóo mú kí ó sá pada sí ilẹ̀ rẹ̀ nígbà tí ó bá gbọ́ ìròyìn kan, òun óo sì jẹ́ kí wọ́n pa á nígbà tí ó bá dé ilẹ̀ rẹ̀.” Rabuṣake gbọ́ pé ọba Asiria ti kúrò ní Lakiṣi láti lọ jagun ní Libina, ó sì lọ sibẹ láti lọ rí i. Nígbà tí ọba Asiria gbọ́ pé Tirihaka, ọba Etiopia, ń kó ogun rẹ̀ bọ̀ láti bá òun jagun, ó ranṣẹ sí Hesekaya, ọba Juda, ó ní kí wọ́n sọ fún un pé, “Má jẹ́ kí Ọlọrun tí o gbẹ́kẹ̀lé tàn ọ́ jẹ pé ọba Asiria kò ní fi ogun kó Jerusalẹmu. O ti gbọ́ ìròyìn ohun tí ọba Asiria ti ṣe sí àwọn tí ó ti bá jagun, pé ó pa wọ́n run patapata ni. Ṣé ìwọ rò pé o lè là? Àwọn baba ńlá mi ti pa àwọn ìlú Gosani, Harani, Resefu ati àwọn ọmọ Edẹni tí wọ́n wà ní Telasari run, àwọn ọlọrun wọn kò sì lè gbà wọ́n. Níbo ni ọba Hamati, ati ti Aripadi, ati ti Sefafaimu, ati ti Hena, ati ti Ifa wà?” Hesekaya ọba gba ìwé náà lọ́wọ́ àwọn iranṣẹ, ó kà á. Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ilé OLUWA, ó tẹ́ ìwé náà sílẹ̀ níwájú OLUWA. Ó gbadura pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí ń gbé láàrin àwọn Kerubu, ìwọ nìkan ni Ọlọrun tí ń jọba lórí gbogbo ilẹ̀ ayé, ìwọ ni o dá ayé ati ọ̀run. Nisinsinyii, bojú wo ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí wa; kí o sì gbọ́ bí Senakeribu ti ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ìwọ Ọlọrun alààyè. OLUWA, àwa mọ̀ pé ní òtítọ́ ni ọba Asiria ti pa ọpọlọpọ àwọn orílẹ̀-èdè run, ó sì ti sọ ilẹ̀ wọn di aṣálẹ̀. Ó ti dáná sun àwọn ọlọrun wọn; ṣugbọn wọn kì í ṣe Ọlọrun tòótọ́, ère lásán tí a fi igi ati òkúta gbẹ́ ni wọ́n, iṣẹ́ ọwọ́ ọmọ eniyan. Nisinsinyii OLUWA Ọlọrun wa, jọ̀wọ́ gbà wá lọ́wọ́ Asiria kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ayé lè mọ̀ pé ìwọ OLUWA nìkan ni ỌLỌRUN.” Nígbà náà ni Aisaya ọmọ Amosi ranṣẹ sí Hesekaya ọba pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ní: Mo ti gbọ́ adura rẹ nípa Senakeribu, ọba Asiria. Ohun tí OLUWA sọ nípa Senakeribu ni pé, ‘Sioni yóo fi ojú tẹmbẹlu rẹ, yóo sì fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà; Jerusalẹmu yóo fi ọ́ rẹ́rìn-ín.’ Ta ni o rò pé ò ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí, tí o sì fi ń ṣe ẹlẹ́yà? Ta ni ò ń kígbe mọ́, tí o sì ń wò ní ìwò ìgbéraga? Èmi Ẹni Mímọ́ Israẹli ni! O rán oníṣẹ́ rẹ láti fi OLUWA ṣe ẹlẹ́yà, o ní, ‘N óo fi ọpọlọpọ kẹ̀kẹ́ ogun mi ṣẹgun àwọn òkè, títí dé òkè tí ó ga jùlọ ní Lẹbanoni; mo gé àwọn igi Kedari gíga rẹ̀ lulẹ̀, ati àwọn igi sipirẹsi rẹ̀ tí ó dára jùlọ, Mo wọ inú igbó rẹ̀ tí ó jìnnà ju lọ, mo sì wọ inú aṣálẹ̀ rẹ̀ tí ó dí jùlọ. Mo gbẹ́ kànga ní ilẹ̀ àjèjì, mo sì mu omi rẹ̀; ẹsẹ̀ àwọn jagunjagun mi ni ó sì gbẹ́ àwọn odò Ijipti.’ “Ṣé o kò mọ̀ pé ó pẹ́ tí mo ti pinnu àwọn nǹkan tí ó ń ṣẹlẹ̀ wọnyi ni? Èmi ni mo fún ọ ní agbára tí o fi sọ àwọn ìlú olódi di òkítì àlàpà. Nítorí náà ni àwọn tí wọn ń gbé inú àwọn ìlú olódi náà ṣe di aláìlágbára, tí ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi. Wọ́n dàbí ìgbà tí atẹ́gùn gbígbóná ìlà oòrùn bá fẹ́ lu koríko tabi ewéko tí ó hù ní orí òrùlé. Ṣugbọn kò sí ohun tí n kò mọ̀ nípa rẹ, mo mọ àtijókòó rẹ, àtijáde rẹ ati àtiwọlé rẹ, ati bí o ti ń ta kò mí. Mo ti gbọ́ ìròyìn ibinu rẹ ati ìgbéraga rẹ, n óo fi ìwọ̀ kọ́ ọ nímú, n óo fi ìjánu bọ̀ ọ́ lẹ́nu, n óo sì fà ọ́ pada sí ibi tí o ti wá.” Nígbà náà ni Aisaya sọ fún Hesekaya ọba pé, “Ohun tí yóo jẹ́ àmì fún ọ nípa àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ nìyí. Ní ọdún yìí ati ọdún tí ń bọ̀, ẹ óo jẹ àjàrà tí ó lalẹ̀ hù, ṣugbọn ní ọdún tí ó tẹ̀lé e, ẹ óo le gbin ohun ọ̀gbìn yín, ẹ óo sì kórè rẹ̀, ẹ óo gbin ọgbà àjàrà, ẹ óo sì jẹ èso àjàrà rẹ̀. Yóo dára fún àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù ní Juda. Wọn yóo dàbí irúgbìn tí gbòǹgbò rẹ̀ wọnú ilẹ̀ lọ tí ó sì ń so èso jáde. Àwọn eniyan yóo là ní Jerusalẹmu, àwọn eniyan yóo sì ṣẹ́kù ni Òkè Sioni, nítorí pé ìtara ni OLUWA yóo fi ṣe é. “Ohun tí OLUWA sọ nípa ọba Asiria ni pé, kò ní wọ inú ìlú yìí, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ta ọfà kankan sí i. Kò sí ọmọ ogun kan tí ó ní apata tí yóo wá sí ẹ̀bá ìlú náà, bẹ́ẹ̀ ni kò ní lè gbìyànjú láti gbógun tì í. Ọ̀nà tí ó gbà wá ni yóo gbà lọ láìwọ ìlú yìí nítorí èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo gbèjà ìlú yìí, n óo sì dáàbò bò ọ́ nítorí ògo mi ati ìlérí tí mo ti ṣe fún Dafidi iranṣẹ mi.” Ní alẹ́ ọjọ́ náà ni angẹli OLUWA lọ sí ibùdó ogun Asiria, ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹsan-an lé ẹẹdẹgbaata (185,000) àwọn ọmọ ogun, wọn kú kí ilẹ̀ ọjọ́ keji tó mọ́. Senakeribu ọba Asiria bá pada sí Ninefe. Ní ọjọ́ kan níbi tí ó ti ń bọ oriṣa ninu ilé Nisiroku, oriṣa rẹ̀, ni Adirameleki ati Ṣareseri, àwọn ọmọ rẹ̀ bá fi idà pa á, wọ́n sì sá lọ sí ilẹ̀ Ararati. Esaradoni ọmọ rẹ̀ bá jọba lẹ́yìn rẹ̀. Ní àkókò kan Hesekaya ṣàìsàn tóbẹ́ẹ̀ tí ó fẹ́rẹ̀ kú. Wolii Aisaya ọmọ Amosi, wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sọ fún un pé, “OLUWA ní kí o palẹ̀ ilé rẹ mọ́ nítorí pé kíkú ni o óo kú, o kò ní yè.” Hesekaya bá kọjú sí ògiri, ó sì gbadura sí OLUWA, ó ní, “Mo bẹ̀ ọ́ OLUWA, ranti bí mo ti sìn ọ́ pẹlu òtítọ́ ati ọkàn pípé, ati bí mo ti ń ṣe ohun tí o fẹ́.” Ó sì sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn. Aisaya jáde kúrò lọ́dọ̀ ọba, ṣugbọn kí ó tó jáde kúrò ní àgbàlá ààfin, OLUWA sọ fún un pé, “Pada lọ sọ́dọ̀ Hesekaya, olórí àwọn eniyan mi, kí o sì sọ fún un pé, ‘Èmi OLUWA Ọlọrun Dafidi baba ńlá rẹ̀ ti gbọ́ adura rẹ̀, mo sì ti rí omijé rẹ̀. N óo wò ó sàn, ní ọjọ́ kẹta, yóo lọ sí ilé OLUWA, n óo sì jẹ́ kí ó gbé ọdún mẹẹdogun sí i. N óo gba òun ati Jerusalẹmu lọ́wọ́ ọba Asiria. N óo sì dáàbò bo ìlú yìí nítorí tèmi fúnra mi ati nítorí ìlérí tí mo ṣe fún Dafidi, iranṣẹ mi.’ ” Aisaya bá sọ fún àwọn iranṣẹ ọba pé kí wọ́n fi èso ọ̀pọ̀tọ́ sí orí oówo rẹ̀, kí ara rẹ̀ lè dá. Hesekaya ọba bèèrè pé, “Kí ni yóo jẹ́ àmì pé OLUWA yóo wò mí sàn, ati pé n óo lọ sí ilé OLUWA ní ọjọ́ kẹta?” Aisaya dáhùn pé, “OLUWA yóo fún ọ ní àmì láti fihàn pé òun yóo mú ìlérí òun ṣẹ. Èwo ni o fẹ́, ninu kí òjìji lọ siwaju ní ẹsẹ̀ mẹ́wàá tabi kí ó pada sẹ́yìn ní ẹsẹ̀ mẹ́wàá?” Hesekaya dáhùn pé, “Ó rọrùn fún òjìji láti lọ siwaju ní ẹsẹ̀ mẹ́wàá, kí ó pada sẹ́yìn ni mo fẹ́.” Aisaya gbadura sí OLUWA, OLUWA sì mú kí òjìji pada sẹ́yìn ní ẹsẹ̀ mẹ́wàá lára àtẹ̀gùn ilé tí ọba Ahasi ṣe. Ní àkókò kan náà ni Merodaki Baladani, ọmọ Baladani, ọba Babiloni, fi ìwé ati ẹ̀bùn ranṣẹ sí Hesekaya nítorí ó gbọ́ pé Hesekaya ń ṣe àìsàn. Hesekaya gba àwọn oníṣẹ́ náà ní àlejò. Ó fi gbogbo ilé ìṣúra rẹ̀, fadaka, wúrà, turari, òróró iyebíye ati gbogbo ohun ìjà rẹ̀ hàn wọ́n. Kò sí ohun kan ninu ilé ìṣúra rẹ̀ ati ní gbogbo ìjọba rẹ̀ tí kò fihàn wọ́n. Nígbà náà ni wolii Aisaya lọ sí ọ̀dọ̀ Hesekaya, ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Níbo ni àwọn ọkunrin wọnyi ti wá, kí ni wọ́n sì sọ fún ọ?” Hesekaya dáhùn pé, “Ọ̀nà jíjìn ni wọ́n ti wá, láti Babiloni.” Aisaya bá tún bèèrè pé, “Kí ni wọ́n rí ninu ààfin rẹ?” Ọba dáhùn, ó ní, “Kò sí ohun kan ninu ilé ìṣúra tí n kò fi hàn wọ́n.” Nígbà náà ni Aisaya sọ fún ọba pé, “OLUWA ní, ‘Àkókò kan ń bọ̀ tí wọn yóo kó gbogbo ohun tí ó wà ninu ààfin rẹ lọ sí Babiloni, gbogbo ohun tí àwọn baba ńlá rẹ ti kó jọ látẹ̀yìnwá títí di òní ni wọn óo kó lọ, wọn kò ní fi nǹkankan sílẹ̀. Wọn yóo kó ninu àwọn ọmọ rẹ lọ fi ṣe ìwẹ̀fà ní ààfin ọba Babiloni.’ ” Hesekaya sọ fún Aisaya pé, “Ọ̀rọ̀ OLUWA tí o sọ dára.” Nítorí ó wí ninu ara rẹ̀ pé, alaafia ati ìfọ̀kànbalẹ̀ yóo sá wà ní àkókò tòun. Gbogbo nǹkan yòókù tí Hesekaya ṣe, ìwà akọni rẹ̀ ati bí ó ti ṣe adágún omi ati ọ̀nà omi wọ inú ìlú ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. Hesekaya kú, wọ́n sì sin ín sinu ibojì àwọn baba rẹ̀; Manase ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Ọmọ ọdún mejila ni Manase nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún marundinlọgọta. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hefisiba. Manase ṣe nǹkan tí ó burú lójú OLUWA nítorí pé ó tẹ̀lé ìwà ìríra àwọn eniyan ilẹ̀ náà, tí OLUWA lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Israẹli. Ó tún àwọn ilé oriṣa tí Hesekaya, baba rẹ̀ ti parun kọ́, ó kọ́ pẹpẹ ìrúbọ fún oriṣa Baali, ó sì gbẹ́ ère oriṣa Aṣera, bí Ahabu, ọba Israẹli, ti gbẹ́ ẹ. Ó sì ń bọ àwọn ìràwọ̀. Ó kọ́ pẹpẹ ìrúbọ oriṣa sinu ilé OLUWA, níbi tí OLUWA ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli láti máa sin òun. Ó kọ́ pẹpẹ ìrúbọ fún àwọn ìràwọ̀ ninu àwọn àgbàlá mejeeji tí wọ́n wà ninu ilé OLUWA. Ó fi ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ sísun, a máa ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ àwọn aláfọ̀ṣẹ, a sì máa ṣe àlúpàyídà. Bẹ́ẹ̀ ni ó máa ń wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn alásọtẹ́lẹ̀ ati àwọn abókùúsọ̀rọ̀. Ó hùwà tí ó burú gidigidi níwájú OLUWA, ó sì rú ibinu OLUWA sókè. Ó gbẹ́ ère Aṣera tí ó gbé sinu ilé OLUWA, ibi tí OLUWA ti sọ fún Dafidi ati Solomoni pé, “Ninu ilé yìí, àní, ní Jerusalẹmu, ni mo yàn láàrin àwọn ìlú àwọn ẹ̀yà mejeejila Israẹli, gẹ́gẹ́ bí ibi tí ẹ óo ti máa sìn mí títí lae. Ati pé bí àwọn ọmọ Israẹli bá júbà àṣẹ mi, tí wọ́n pa òfin mi, tí Mose, iranṣẹ mi, fún wọn mọ́, n kò ní jẹ́ kí á lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá wọn.” Ṣugbọn àwọn ọmọ ilẹ̀ Juda kò júbà OLUWA, Manase sì mú kí wọ́n dẹ́ṣẹ̀ tí ó burú ju èyí tí àwọn eniyan ilẹ̀ náà tẹ́lẹ̀ dá lọ, àní, àwọn tí OLUWA lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Israẹli. OLUWA sọ láti ẹnu àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀, pé, “Manase ọba ti ṣe àwọn ohun ìríra wọnyi, wọ́n burú ju èyí tí àwọn ará Kenaani ṣe lọ. Ó sì mú kí Juda dẹ́ṣẹ̀ nípa pé wọ́n ń bọ àwọn ère rẹ̀. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun Israẹli ní òun óo mú ìparun wá sórí Jerusalẹmu ati Juda, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo jẹ́ ìyàlẹ́nu gidigidi fún ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́. Ó ní òun óo jẹ Jerusalẹmu níyà bí òun ti jẹ Samaria níyà. Ó ní bí òun ti ṣe sí ìdílé Ahabu ati àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni òun óo gbá àwọn eniyan náà kúrò ní Jerusalẹmu, bí àwo tí a nù tí a sì da ojú rẹ̀ bolẹ̀. OLUWA ní òun óo kọ àwọn eniyan òun yòókù sílẹ̀, òun óo fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, ọ̀tá yóo ṣẹgun wọn, wọn yóo sì kó wọn lọ bí ìkógun. Nítorí pé wọ́n ti ṣe ohun burúkú lójú òun, wọ́n sì ti mú òun bínú láti ìgbà tí àwọn baba ńlá wọn ti kúrò ní Ijipti, àní títí di òní olónìí.” Manase pa ọpọlọpọ àwọn eniyan aláìṣẹ̀ títí tí ẹ̀jẹ̀ fi ń ṣàn ní ìgboro Jerusalẹmu. Ó tún fa àwọn eniyan Juda sinu ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà; nípa bẹ́ẹ̀ ó mú kí wọ́n ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA. Gbogbo nǹkan yòókù tí Manase ṣe ati àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. Manase kú, wọ́n sì sin ín sinu ọgba Usa tí ó wà ní ààfin. Amoni ọmọ rẹ̀, sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Ẹni ọdún mejilelogun ni Amoni nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún meji. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Meṣulemeti ọmọ Harusi ará Jotiba. Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA bí Manase, baba rẹ̀ ti ṣe. Ó tẹ̀ sí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀, ó sì bọ àwọn ère tí baba rẹ̀ bọ. Ó kọ OLUWA Ọlọrun àwọn baba ńlá rẹ̀ sílẹ̀, kò sì júbà àṣẹ rẹ̀. Àwọn iranṣẹ rẹ̀ dìtẹ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì pa á ní ààfin rẹ̀. Àwọn eniyan Juda pa àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ mọ́ Amoni ọba, wọ́n sì fi Josaya ọmọ rẹ̀ jọba lẹ́yìn rẹ̀. Gbogbo nǹkan yòókù tí Amoni ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. Wọ́n sin òkú rẹ̀ sinu ibojì tí ó wà ninu ọgbà Usa ní ààfin. Josaya, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Ọmọ ọdún mẹjọ ni Josaya nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkanlelọgbọn. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Jedida ọmọ Adaya ará Bosikati. Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA, ó tẹ̀ sí ọ̀nà Dafidi, baba ńlá rẹ̀, kò sì ṣe nǹkankan tí ó lòdì sí àpẹẹrẹ tí Dafidi fi lélẹ̀. Ní ọdún kejidinlogun tí Josaya jọba, ó rán Ṣafani, akọ̀wé rẹ̀, ọmọ Asalaya, ọmọ Meṣulamu, sí ilé OLUWA pé kí ó lọ sí ọ̀dọ̀ Hilikaya olórí alufaa, kí ó ṣírò iye owó tí àwọn alufaa tí wọ́n wà lẹ́nu ọ̀nà ti gbà lọ́wọ́ àwọn eniyan, kí ó gbé owó náà fún àwọn tí wọ́n ń ṣe àkóso àtúnṣe ilé OLUWA. Àwọn ni wọn yóo máa san owó fún àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àwọn ọ̀mọ̀lé ati àwọn agbẹ́kùúta, kí wọ́n sì ra igi ati òkúta tí wọn yóo lò fún àtúnṣe ilé OLUWA. Ó ní àwọn tí wọ́n ń ṣe àkóso àtúnṣe ilé náà kò ní nílò láti ṣe ìṣirò owó tí wọn ń ná, nítorí pé gbogbo wọn ni wọ́n jẹ́ olóòótọ́. Ṣafani jíṣẹ́ ọba fún Hilikaya; Hilikaya olórí alufaa, sì sọ fún un pé òun ti rí ìwé òfin ninu ilé OLUWA. Ó fún Ṣafani ní ìwé náà, ó sì kà á. Ṣafani bá pada lọ jíṣẹ́ fún ọba, ó sọ fún ọba pé, àwọn iranṣẹ rẹ̀ ti kó owó tí ó wà ninu ilé OLUWA fún àwọn tí wọ́n ń ṣe àkóso àtúnṣe ilé OLUWA, ati pé Hilikaya fún òun ní ìwé kan; ó sì kà á sí etígbọ̀ọ́ ọba. Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ inú ìwé náà, ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn. Ó bá pàṣẹ fún Hilikaya alufaa, Ahikamu ọmọ Ṣafani, Akibori ọmọ Mikaya, Ṣafani, akọ̀wé, ati Asaya, iranṣẹ ọba pé, “Ẹ lọ bèèrè ohun tí a kọ sinu ìwé yìí lọ́wọ́ OLUWA fún èmi ati fún gbogbo eniyan Juda. OLUWA ń bínú sí wa gidigidi nítorí pé àwọn baba ńlá wa kò ṣe ohun tí ìwé yìí pa láṣẹ fún wa.” Hilikaya alufaa, ati Ahikamu ati Akibori ati Ṣafani ati Asaya bá lọ wádìí lọ́wọ́ wolii obinrin kan tí ń jẹ́ Hulida, tí ń gbé apá keji Jerusalẹmu. Ọkọ rẹ̀ ni Ṣalumu ọmọ Tikifa, ọmọ Harihasi tíí máa ń ṣe ìtọ́jú yàrá tí wọn ń kó aṣọ pamọ́ sí. Wọ́n sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún obinrin náà. Ó bá rán wọn pada, ó ní: “Ẹ lọ sọ fún ẹni tí ó ran yín sí mi pé, ‘OLUWA ní, “Wò ó n óo jẹ Jerusalẹmu ati àwọn eniyan inú rẹ̀ níyà bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé tí ọba Juda kà. Nítorí pé wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n ń sun turari sí àwọn oriṣa láti mú mi bínú nítorí iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Nítorí náà, inú mi yóo ru sí ibí yìí, kò sì ní rọlẹ̀. Ṣugbọn níti ọba Juda tí ó sọ pé kí ẹ lọ wádìí lọ́wọ́ OLUWA, ẹ sọ fún un pé, OLUWA Ọlọrun Israẹli ní: Nípa ọ̀rọ̀ tí ó ti gbọ́, nítorí pé ó ronupiwada, ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú OLUWA, ó fa aṣọ rẹ̀ ya ó sì sun ẹkún nígbà tí ó gbọ́ ìlérí ìjìyà tí mo ṣe nípa Jerusalẹmu ati àwọn eniyan ibẹ̀, pé n óo sọ Jerusalẹmu di ahoro ati ibi tí àwọn eniyan yóo máa lo orúkọ rẹ̀ láti gégùn-ún. Ṣugbọn mo ti gbọ́ adura rẹ̀ nítorí pé ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì sọkún níwájú mi. Nítorí náà, n kò ní fi ìyà jẹ Jerusalẹmu nígbà tí ó wà láàyè, n óo jẹ́ kí ó kú ní alaafia.” ’ ” Àwọn ọkunrin náà sì lọ jíṣẹ́ fún Josaya ọba. Josaya bá pe ìpàdé gbogbo àwọn olórí Juda ati Jerusalẹmu. Gbogbo wọn lọ sí ilé OLUWA pẹlu àwọn alufaa ati àwọn wolii ati gbogbo àwọn eniyan, àtọmọdé àtàgbà wọn. Ọba bá ka ìwé majẹmu tí wọ́n rí ninu ilé OLUWA sí etígbọ̀ọ́ wọn. Ọba dúró sí ààyè rẹ̀, lẹ́bàá òpó, ó bá OLUWA dá majẹmu pé òun óo máa rìn ní ọ̀nà OLUWA ati láti pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ ati láti mú gbogbo ohun tí ó wà ninu Ìwé náà ṣẹ. Gbogbo àwọn eniyan sì ṣe ìlérí láti pa majẹmu náà mọ́. Josaya bá pàṣẹ fún Hilikaya olórí alufaa, ati àwọn alufaa yòókù ati àwọn tí wọn ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA, pé kí wọ́n kó gbogbo ohun èlò ìsìn oriṣa Baali, ati ti oriṣa Aṣera, ati ti àwọn ìràwọ̀ jáde. Ọba jó àwọn ohun èlò náà níná lẹ́yìn odi ìlú, lẹ́bàá àfonífojì Kidironi, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n kó eérú wọn lọ sí Bẹtẹli. Gbogbo àwọn alufaa tí àwọn ọba Juda ti yàn láti máa rúbọ lórí pẹpẹ oriṣa ní àwọn ìlú Juda ati ní agbègbè Jerusalẹmu ni Josaya dá dúró, ati gbogbo àwọn tí wọn ń rúbọ sí oriṣa Baali, sí oòrùn, òṣùpá, àwọn ìràwọ̀, ati àwọn nǹkan tí wọ́n wà ní òfuurufú. Ó kó gbogbo àwọn ère oriṣa Aṣera tí ó wà ninu ilé OLUWA lọ sí àfonífojì Kidironi lẹ́yìn Jerusalẹmu. Ó sun wọ́n níná níbẹ̀, ó lọ̀ wọ́n lúbúlúbú, ó sì fọ́n eérú wọn ká sórí ibojì àwọn eniyan. Ó wó gbogbo ibi tí àwọn tí wọ́n máa ń ṣe panṣaga fún ìsìn Aṣera ń gbé létí ilé OLUWA lulẹ̀, níbi tí àwọn obinrin ti máa ń hun aṣọ fún ìsìn Aṣera. Gbogbo àwọn alufaa tí wọ́n wà káàkiri ilẹ̀ Juda ni ó mú wá sí Jerusalẹmu, ó sì ba gbogbo àwọn pẹpẹ ìrúbọ tí wọ́n ti ń rúbọ jẹ́. Ó wó pẹpẹ ìrúbọ tí ó wà ní ẹnubodè, tí Joṣua, baálẹ̀ ìlú kọ́, tí ó wà ní apá òsì, bí eniyan bá ti fẹ́ wọ ìlú. Kò gba àwọn alufaa náà láàyè láti ṣiṣẹ́ ninu ilé OLUWA, ṣugbọn wọ́n lè jẹ ninu àkàrà tí wọn kò fi ìwúkàrà ṣe, tí ó jẹ́ ti àwọn alufaa ẹlẹgbẹ́ wọn. Josaya Ọba wó ilé oriṣa Tofeti tí ó wà ní àfonífojì Hinomu, kí ẹnikẹ́ni má baà lè fi ọmọkunrin tabi ọmọbinrin rẹ̀ rúbọ sí oriṣa Moleki mọ́. Ó tú gbogbo ẹṣin tí àwọn ọba Juda ti yà sọ́tọ̀ fún ìsìn oòrùn, ní ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA, lẹ́bàá yàrá Natani Meleki, ìwẹ̀fà tí ó wà ní agbègbè ilé OLUWA; ó sì dáná sun àwọn kẹ̀kẹ́ ogun tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún ìsìn oòrùn. Ó wó àwọn pẹpẹ ìrúbọ tí àwọn ọba Juda kọ́ sórí ilé Ahasi ninu ààfin lulẹ̀, pẹlu àwọn pẹpẹ ìrúbọ tí Manase kọ́ sinu àwọn àgbàlá meji tí ó wà ninu ilé OLUWA. Ó fọ́ gbogbo wọn túútúú, ó sì kó wọn dà sí àfonífojì Kidironi. Josaya wó gbogbo ibi gíga tí wọn tún ń pè ní òkè ìdíbàjẹ́, tí Solomoni kọ́ sí apá ìhà ìlà oòrùn Jerusalẹmu, ní ìhà gúsù Òkè Olifi, fún àwọn oriṣa Aṣitoreti, ohun ìríra àwọn ará Sidoni, ati Kemoṣi, ohun ìríra àwọn ará Moabu, ati fún Milikomu, ohun ìríra àwọn ará Amoni. Josaya ọba fọ́ àwọn òpó òkúta túútúú, ó gé àwọn ère oriṣa Aṣera, ó sì kó egungun eniyan sí ibi tí wọ́n ti hú wọn jáde. Josaya wó ilé oriṣa tí Jeroboamu ọba, ọmọ Nebati, ẹni tí ó mú Israẹli ṣẹ̀, kọ́ sí Bẹtẹli. Josaya wó pẹpẹ ìrúbọ tí ó wà níbẹ̀, ó fọ́ òkúta rẹ̀ túútúú, ó lọ̀ wọ́n lúbúlúbú, ó sì jó ère Aṣera pẹlu. Bí Josaya ti yí ojú pada, ó rí àwọn ibojì kan lórí òkè. Ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n kó àwọn egungun inú wọn jáde, kí wọ́n sì jó wọn lórí pẹpẹ ìrúbọ náà; ó sì fi bẹ́ẹ̀ sọ pẹpẹ ìrúbọ náà di ìbàjẹ́, gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ tí wolii Ọlọrun ti sọ. Nígbà tí Josaya ọba rí ibojì wolii tí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ náà, ó bèèrè pé, “Ọ̀wọ̀n ibojì ta ni mò ń wò lọ́ọ̀ọ́kán yìí?” Àwọn tí wọ́n wà ní Bẹtẹli sì dáhùn pé, “Ibojì wolii tí ó wá láti Juda tí ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ohun tí ò ń ṣe sí pẹpẹ ìrúbọ yìí ni.” Josaya bá pàṣẹ pé kí wọ́n fi sílẹ̀ bí ó ti wà, kí wọ́n má ṣe kó egungun rẹ̀. Nítorí náà, wọn kò kó egungun rẹ̀ ati egungun wolii tí ó wá láti Samaria. Ní gbogbo àwọn ìlú Israẹli ni Josaya ti wó àwọn ilé oriṣa tí àwọn ọba Israẹli kọ́ tí ó bí OLUWA ninu. Bí ó ti ṣe pẹpẹ ìrúbọ tí ó wà ní Bẹtẹli ni ó ṣe àwọn pẹpẹ ìrúbọ náà. Ó pa gbogbo àwọn alufaa ibi ìrúbọ lórí pẹpẹ ìrúbọ wọn, ó sì jó egungun eniyan lórí gbogbo àwọn pẹpẹ ìrúbọ náà. Lẹ́yìn náà, ó pada sí Jerusalẹmu. Josaya pàṣẹ pé kí àwọn eniyan náà ṣe Àjọ̀dún Àjọ Ìrékọjá fún ògo OLUWA Ọlọrun wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ninu ìwé majẹmu; nítorí pé wọn kò ti ṣe Àjọ̀dún Àjọ Ìrékọjá mọ́ láti àkókò àwọn onídàájọ́ ati ti àwọn ọba Israẹli ati Juda. Ṣugbọn ní ọdún kejidinlogun tí Josaya ti jọba ni àwọn eniyan ṣe Àjọ̀dún Àjọ Ìrékọjá fún ògo OLUWA ní Jerusalẹmu. Josaya ọba lé gbogbo àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ati àwọn oṣó jáde kúrò ní Jerusalẹmu, ó sì kó àwọn ère, àwọn oriṣa, ati gbogbo ohun ìbọ̀rìṣà kúrò ní Jerusalẹmu ati ilẹ̀ Juda, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ninu òfin tí ó wà ninu ìwé tí Hilikaya olórí alufaa rí ninu ilé OLUWA. Ṣáájú Josaya ati lẹ́yìn rẹ̀, kò sí ọba kankan tí ó fi gbogbo ọkàn rẹ̀, gbogbo ẹ̀mí rẹ̀ ati gbogbo agbára rẹ̀ sin Ọlọrun, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ninu gbogbo òfin Mose. Ṣugbọn sibẹsibẹ ibinu gbígbóná OLUWA tí ó ti ru sókè sí Juda nítorí ìwà burúkú Manase kò rọlẹ̀. OLUWA sọ pé, “N óo ṣe ohun tí mo ṣe sí Israẹli sí Juda, n óo pa àwọn eniyan Juda run, n óo sì kọ Jerusalẹmu, ìlú tí mo yàn sílẹ̀, ati ilé OLUWA tí mo yàn fún ìsìn mi.” Gbogbo nǹkan yòókù tí Josaya ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. Ní àkókò tí Josaya jọba ni Neko, ọba Ijipti kó ogun rẹ̀ wá sí etí odò Yufurate láti ran ọba Asiria lọ́wọ́. Josaya pinnu láti dá ogun Ijipti pada ní Megido, ṣugbọn ó kú lójú ogun náà. Àwọn olórí ogun rẹ̀ gbé òkú rẹ̀ sinu kẹ̀kẹ́ ogun kan láti Megido wọn gbé e wá sí Jerusalẹmu, wọ́n sì sin ín sinu ibojì rẹ̀. Àwọn eniyan Juda sì fi òróró yan Jehoahasi ọmọ rẹ̀ ní ọba. Ẹni ọdún mẹtalelogun ni Jehoahasi nígbà tí ó jọba ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹta. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hamutali, ọmọ Jeremaya, ará Libina. Òun náà ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá rẹ̀. Neko ọba Ijipti mú Jehoahasi ní ìgbèkùn ní Ribila ní ilẹ̀ Hamati, kí ó má baà jọba lórí Jerusalẹmu mọ́. Ó sì mú kí Juda san ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti fadaka ati ìwọ̀n talẹnti wúrà kan bí ìṣákọ́lẹ̀. Neko sì fi Eliakimu, ọmọ Josaya, jọba dípò rẹ̀, ṣugbọn ó yí orúkọ rẹ̀ pada sí Jehoiakimu. Neko mú Jehoahasi lọ sí Ijipti, ibẹ̀ ni ó sì kú sí. Jehoiakimu ọba gba owó orí lọ́wọ́ àwọn eniyan gẹ́gẹ́ bí ọrọ̀ wọn ti pọ̀ tó, láti rí owó san ìṣákọ́lẹ̀ fún ọba Ijipti gẹ́gẹ́ bí ó ti pa á láṣẹ fún un. Jehoiakimu jẹ́ ẹni ọdún mẹẹdọgbọn nígbà tí ó jọba, ó sì jọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkanla. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Sebida, ọmọ Pedaaya, láti ìlú Ruma. Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá rẹ̀. Ní àkókò ìjọba Jehoiakimu ni Nebukadinesari, ọba Babiloni gbógun ti Jerusalẹmu, Jehoiakimu sì di iranṣẹ rẹ̀ fún ọdún mẹta. Lẹ́yìn náà, ó pada lẹ́yìn Nebukadinesari, ó sì ṣọ̀tẹ̀ sí i. OLUWA bá rán àwọn ọmọ ogun Kalidea, ati ti Siria, ti Moabu, ati ti Amoni, láti pa Juda run bí ọ̀rọ̀ ti OLUWA sọ láti ẹnu àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀. Ìjìyà yìí dé bá Juda láti ọ̀dọ̀ OLUWA, láti pa wọ́n run kúrò níwájú rẹ̀, nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Manase ọba, ati nítorí ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí ó ti ta sílẹ̀, nítorí tí ó ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní gbogbo ìgboro Jerusalẹmu, OLUWA kò ní dáríjì í. Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoiakimu ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. Jehoiakimu kú, Jehoiakini ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Ọba Ijipti kò lè jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ mọ́, nítorí pé ọba Babiloni ti gba gbogbo ilẹ̀ ọba Ijipti láti odò Ijipti títí dé odò Yufurate. Ẹni ọdún mejidinlogun ni Jehoiakini nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹta. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Nehuṣita, ọmọ Elinatani ará Jerusalẹmu. Òun náà ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA gẹ́gẹ́ bíi baba rẹ̀. Ní àkókò náà ni àwọn ọmọ ogun Nebukadinesari, ọba Babiloni, lọ gbógun ti Jerusalẹmu, wọ́n sì dó tì í. Ní àkókò tí wọ́n dó ti ìlú náà ni Nebukadinesari ọba Babiloni lọ sibẹ. Ní ọdún kẹjọ tí ọba Babiloni jọba ni Jehoiakini ọba Juda jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ọba Babiloni, ó sì jọ̀wọ́ ìyá rẹ̀, àwọn iranṣẹ rẹ̀, àwọn ìjòyè rẹ̀ ati àwọn òṣìṣẹ́ ààfin rẹ̀ pẹlu, ọba Babiloni bá kó wọn ní ìgbèkùn. Ó kó gbogbo àwọn ìṣúra ilé OLUWA ati àwọn ìṣúra tí ó wà ní ààfin. Gbogbo ohun èèlò wúrà tí wọ́n wà ninu ilé OLUWA, tí Solomoni ọba Israẹli ṣe, ni ó gé sí wẹ́wẹ́, gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti sọ tẹ́lẹ̀. Ó kó gbogbo Jerusalẹmu ní ìgbèkùn; gbogbo àwọn ìjòyè, àwọn akọni, àwọn oníṣẹ́ ọwọ́, ati àwọn alágbẹ̀dẹ, gbogbo wọn jẹ́ ẹgbaarun (10,000), kò ṣẹ́ku ẹyọ ẹnìkan ní ìlú náà, àfi àwọn talaka. Ó kó ọba Jehoiakini, ati ìyá rẹ̀, ati àwọn aya rẹ̀, àwọn ìwẹ̀fà rẹ̀ ati àwọn ìjòyè ilẹ̀ náà ní ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babiloni. Ọba Babiloni kó ẹẹdẹgbaarin (7,000) àwọn akọni ní ìgbèkùn ati ẹgbẹrun kan (1,000) àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ ati alágbẹ̀dẹ, gbogbo wọn jẹ́ alágbára tí wọ́n lè jagun. Ó fi Matanaya, arakunrin Jehoiakini jọba dípò rẹ̀, ó sì yí orúkọ rẹ̀ pada sí Sedekaya. Ẹni ọdún mọkanlelogun ni Sedekaya nígbà tí ó wà lórí oyè, ó sì jọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkanla. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hamutali, ọmọ Jeremaya ará Libina. Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jehoiakimu baba rẹ̀. Nítorí náà, OLUWA bínú sí Jerusalẹmu ati Juda; ó sì lé wọn kúrò níwájú rẹ̀. Sedekaya sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Babiloni. Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù kẹwaa ọdún kẹsan-an ìjọba rẹ̀, Nebukadinesari, ọba Babiloni, òun ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti Jerusalẹmu, wọ́n dó tì í, wọ́n sì mọ odi yí i ká. Wọ́n dó ti ìlú náà títí di ọdún kọkanla ìjọba Sedekaya. Ní ọjọ́ kẹsan-an oṣù kẹrin, ìyàn náà mú láàrin ìlú tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn eniyan kò fi rí oúnjẹ jẹ mọ́. Nígbà náà ni wọ́n lu odi ìlú náà, ọba ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì gba ibẹ̀ sá jáde lóru. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Kalidea yí ìlú náà po, wọ́n lu odi ìlú náà, wọ́n gba ẹnu ọ̀nà tí ó wà láàrin odi mejeeji lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọgbà ọba, wọ́n sì gba ọ̀nà tí ó lọ sí Araba. Ṣugbọn àwọn ọmọ ogun Kalidea lépa Sedekaya, wọ́n bá a ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹriko, gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì túká kúrò lẹ́yìn rẹ̀. Ọwọ́ wọn tẹ Sedekaya, wọ́n bá mú un lọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni ní Ribila, ó sì dá ẹjọ́ fún un. Wọ́n pa àwọn ọmọ Sedekaya lójú rẹ̀, lẹ́yìn náà ni Nebukadinesari ọba yọ ojú Sedekaya, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó sì mú un lọ sí Babiloni. Ní ọjọ́ keje oṣù karun-un ọdún kọkandinlogun ìjọba Nebukadinesari, ọba Babiloni, Nebusaradani, tí ń ṣiṣẹ́ fún ọba Babiloni, tí ó sì tún jẹ́ olórí àwọn tí ń ṣọ́ Babiloni wá sí Jerusalẹmu. Ó sun ilé OLUWA níná, ati ilé ọba ati gbogbo ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu. Gbogbo àwọn ilé ńláńlá tí ó wà níbẹ̀ ni ó sì dáná sun. Gbogbo àwọn ọmọ ogun Kalidea, tí wọ́n wà pẹlu olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba wó gbogbo odi Jerusalẹmu lulẹ̀ patapata. Nebusaradani kó àwọn tí wọ́n kù láàrin ìlú ati àwọn tí wọ́n sá tọ ọba Babiloni lọ, pẹlu ogunlọ́gọ̀ àwọn yòókù lọ sí ìgbèkùn. Ṣugbọn ó fi díẹ̀ ninu àwọn talaka sílẹ̀ láti máa tọ́jú ọgbà àjàrà ati láti máa dáko. Àwọn ọmọ ogun Kalidea fọ́ àwọn òpó bàbà tí ó wà ninu ilé OLUWA ati agbada bàbà ńlá tí ó wà ninu ilé OLUWA pẹlu ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀, wọ́n fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́, wọ́n sì kó gbogbo bàbà wọn lọ sí Babiloni. Wọ́n kó àwọn ìkòkò, àwọn ọ̀kọ̀, àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi ń pa iná lẹ́nu àtùpà, àwọn àwo turari ati àwọn ohun èlò bàbà tí wọ́n máa ń lò fún ìsìn ninu ilé OLUWA. Bákan náà, wọ́n kó àwọn àwo ìfọnná, ati àwọn àwo kòtò, gbogbo ohun tí ó jẹ́ ti wúrà ati fadaka, ni olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba Babiloni kó lọ. Bàbà tí Solomoni fi ṣe àwọn òpó mejeeji, agbada omi ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ kọjá wíwọ̀n. Gíga ọ̀kan ninu àwọn òpó náà jẹ́ igbọnwọ mejidinlogun, ọpọ́n idẹ tí ó wà lórí rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ mẹta, wọ́n fi bàbà ṣe ẹ̀wọ̀n bí ẹ̀gbà ọrùn ati pomegiranate yí ọpọ́n náà ká, òpó keji sì dàbí ti àkọ́kọ́ pẹlu ẹ̀wọ̀n bàbà náà. Olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba Babiloni mú Seraya olórí alufaa, ati Sefanaya igbákejì alufaa, ati àwọn aṣọ́nà mẹta. Ó sì mú ọ̀gágun tí ń ṣe àkóso àwọn ọmọ ogun ní ìlú ati àwọn aṣojú ọba marun-un tí ó rí ninu ìlú ati akọ̀wé olórí ogun, tí ń kọ orúkọ àwọn eniyan ilẹ̀ náà sílẹ̀ fún ogun jíjà, ati ọgọta ọkunrin tí ó rí ninu ìlú náà. Nebusaradani kó gbogbo wọn lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babiloni ní Ribila. Ọba Babiloni lù wọ́n, ó sì pa wọ́n sórí ilẹ̀ Hamati. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ṣe kó Juda ní ìgbèkùn kúrò lórí ilẹ̀ rẹ̀. Nebukadinesari ọba Babiloni yan Gedalaya ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani ní gomina lórí àwọn tí wọ́n kù ní ilẹ̀ Juda. Nígbà tí àwọn olórí ogun tí wọ́n wà ní ìgbèríko pẹlu àwọn ọmọ ogun wọn gbọ́ pé ọba Babiloni ti fi Gedalaya ọmọ Ahikamu ṣe Gomina ní ilẹ̀ Juda, àwọn pẹlu àwọn eniyan wọn wá sí ọ̀dọ̀ Gedalaya ní Misipa. Àwọn tí wọ́n wá ni Iṣimaeli, ọmọ Netanaya, Johanani, ọmọ Karea, Seraya, ọmọ Tanhumeti, ará Netofa, ati Jaasanaya, ọmọ ará Maakati. Gedalaya bá búra fún wọn, ó ní: “Ẹ má ṣe bẹ̀rù nítorí àwọn olórí Kalidea, ẹ máa gbé ilẹ̀ náà kí ẹ sì máa sin ọba Babiloni, yóo sì dára fun yín.” Ṣugbọn ní oṣù keje Iṣimaeli, ọmọ Netanaya, ọmọ Eliṣama, láti ìdílé ọba, pẹlu àwọn ọkunrin mẹ́wàá dojú kọ Gedalaya, wọ́n sì pa òun, ati àwọn Juu ati àwọn ará Kalidea tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ní Misipa. Ni gbogbo wọn, àtọmọdé, àtàgbà, ati àwọn olórí ogun bá gbéra, wọ́n kó lọ sí Ijipti, nítorí ẹ̀rù àwọn ará Kalidea bà wọ́n. Ní ọdún kẹtadinlogoji lẹ́yìn tí wọ́n ti mú Jehoiakini ọba Juda lọ sí ìgbèkùn, ní ọjọ́ kẹtadinlọgbọn oṣù kejila ọdún náà, Efilimerodaki, ọba Babiloni, gbé ọ̀rọ̀ Jehoiakini yẹ̀wò, ní ọdún tí ó gorí oyè, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n tú u sílẹ̀ kúrò ní ẹ̀wọ̀n. Ó bá a sọ̀rọ̀ rere, ó sì fi sí ipò tí ó ga ju ti gbogbo àwọn ọba tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ní Babiloni lọ. Jehoiakini bọ́ aṣọ ẹ̀wọ̀n kúrò lọ́rùn, ó sì ń bá ọba jẹun lórí tabili ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. Ọba Babiloni rí i pé òun ń pèsè ohun tí ó nílò ní ojoojumọ fún un, títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. Adamu bí Seti, Seti bí Enọṣi. Enọṣi bí Kenaani, Kenaani bí Mahalaleli, Mahalaleli bí Jaredi; Jaredi bí Enọku, Enọku bí Metusela, Metusela bí Lamẹki; Lamẹki bí Noa, Noa bí Ṣemu, Hamu, ati Jafẹti. Àwọn ọmọ Jafẹti ni Gomeri, Magogu, Madai, Jafani, Tubali, Meṣeki ati Tirasi. Gomeri ni baba ńlá àwọn ọmọ Aṣikenasi, Difati ati Togama. Jafani ni baba ńlá àwọn ọmọ Eliṣa, Taṣiṣi, ati àwọn ará Kitimu, ati Rodọni. Hamu ni baba Kuṣi, Ijipti, Puti ati Kenaani, Kuṣi bí Ṣeba, Hafila, Sabita, Raama ati Sabiteka; Raama ni baba Ṣeba ati Dedani, Kuṣi bí Nimrodu. Nimrodu yìí ni ẹni kinni tí ó di akikanju ati alágbára lórí ilẹ̀ ayé. Ijipti ni baba àwọn ará Lidia ati ti Anamu, ti Lehabu, ati ti Nafitu; àwọn ará Patirusimu ati ti Kasilu tíí ṣe baba ńlá àwọn ará Filistia ati àwọn ará Kafito. Àkọ́bí Kenaani ní Sidoni, lẹ́yìn rẹ̀ ó bí Heti, Kenaani yìí náà ni baba ńlá àwọn ará Jebusi, àwọn ará Amori, ati àwọn ará Girigaṣi; àwọn ará Hifi, àwọn ará Ariki ati àwọn ará Sini; àwọn ará Arifadi, àwọn ará Semari ati àwọn ará Hamati. Ṣemu ni baba Elamu, Aṣuri, ati Apakiṣadi, Ludi, Aramu, ati Usi, Huli, Geteri ati Meṣeki. Apakiṣadi ni baba Ṣela, Ṣela ni baba Eberi, Eberi bí ọmọkunrin meji: Ekinni ń jẹ́ Pelegi, (nítorí pé ní àkókò tirẹ̀ ni àwọn eniyan ayé pín sí meji); ọmọ Eberi keji sì ń jẹ́ Jokitani, Jokitani ni ó bí Alimodadi, Ṣelefu, Hasarimafeti, ati Jera; Hadoramu, Usali, ati Dikila; Ebali, Abimaeli, ati Ṣeba, Ofiri, Hafila ati Jobabu; Àwọn ni àwọn ọmọ Jokitani. Arọmọdọmọ Ṣemu títí fi dé orí Abramu nìyí: Ṣemu, Apakiṣadi, Ṣela; Eberi, Pelegi, Reu; Serugi, Nahori, Tẹra; Abramu, tí a tún ń pè ní Abrahamu. Àwọn ọmọ Abrahamu ni Isaaki ati Iṣimaeli. Àkọsílẹ̀ ìran wọn nìyí: Nebaiotu ni àkọ́bí Iṣimaeli, lẹ́yìn náà ni ó bí Kedari, Adibeeli, ati Mibisamu; Miṣima, Duma ati Masa; Hadadi ati Tema; Jeturi, Nafiṣi, ati Kedema. Abrahamu ní obinrin kan tí ń jẹ́ Ketura. Ó bí àwọn ọmọ mẹfa wọnyi fún Abrahamu: Simirani, Jokiṣani ati Medani; Midiani, Iṣibaki ati Ṣua. Àwọn ọmọ ti Jokiṣani ni: Ṣeba ati Dedani. Àwọn ọmọ marun-un tí Midiani bí ni Efa, Eferi ati Hanoku, Abida ati Elidaa. Gbogbo wọn jẹ́ arọmọdọmọ Ketura. Abrahamu ni baba Isaaki. Àwọn ọmọ Isaaki meji ni Esau ati Jakọbu. Àwọn ọmọ Esau ni Elifasi, Reueli, ati Jeuṣi; Jalamu ati Kora. Àwọn ọmọ Elifasi ni Temani, Omari ati Sefi; Gatamu, Kenasi, Timna ati Amaleki. Àwọn ọmọ Reueli ni Nahati, Sera, Ṣama ati Misa. Àwọn ọmọ Seiri ni Lotani, Ṣobali ati Sibeoni; Ana, Diṣoni, Eseri ati Diṣani. Àwọn ọmọ Lotani ni Hori ati Homami. Lotani ní arabinrin kan tí ń jẹ́ Timna. Àwọn ọmọ Ṣobali ni Aliani, Manahati ati Ebali; Ṣefi ati Onamu. Sibeoni ni baba Aia ati Ana. Ana ni baba Diṣoni. Àwọn ọmọ Diṣoni ni Hamirani, Eṣibani, Itirani ati Kerani. Eseri ló bí Bilihani, Saafani ati Jaakani. Diṣani ni baba Usi ati Arani. Àwọn ọba tí wọ́n jẹ ní ilẹ̀ Edomu, kí ọba kankan tó jẹ ní ilẹ̀ Israẹli nìwọ̀nyí: Bela, ọmọ Beori; orúkọ ìlú rẹ̀ ni Dinhaba. Nígbà tí Bela kú, Jobabu, ọmọ Sera, ará Bosara, jọba tẹ̀lé e. Nígbà tí Jobabu kú, Huṣamu, ará ìlú kan ní agbègbè Temani, jọba tẹ̀lé e. Nígbà tí Huṣamu kú, Hadadi, ọmọ Bedadi, tí ó ṣẹgun àwọn ará Midiani ní ilẹ̀ Moabu, jọba tẹ̀lé e. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Afiti. Nígbà tí Hadadi kú, Samila ará Masireka, jọba tẹ̀lé e. Nígbà tí Samila kú, Ṣaulu ará Rehoboti létí odò Yufurate, jọba tẹ̀lé e. Nígbà tí Ṣaulu kú, Baali Hanani, ọmọ Akibori, jọba tẹ̀lé e. Nígbà tí Baali Hanani kú, Hadadi, jọba tẹ̀lé e. Ìlú tirẹ̀ ni Pau. Iyawo rẹ̀ ni Mehetabeli, ọmọ Matiredi, ìyá rẹ̀ àgbà ni Mesahabu. Nígbà tí ó yá, Hadadi náà kú. Àwọn ìjòyè ẹ̀yà Edomu nìwọ̀nyí: Timna, Alia, ati Jeteti; Oholibama, Ela, ati Pinoni, Kenasi, Temani, ati Mibisari, Magidieli ati Iramu. Àwọn ọmọ Israẹli nìwọ̀nyí: Reubẹni, Simeoni, ati Lefi; Juda, Isakari, ati Sebuluni; Dani, Josẹfu, ati Bẹnjamini; Nafutali, Gadi ati Aṣeri. Juda bí ọmọ marun-un. Batiṣua, aya rẹ̀, ará Kenaani, bí ọmọ mẹta fún un: Eri, Onani ati Ṣela. Eri, àkọ́bí Juda, jẹ́ eniyan burúkú lójú OLUWA, OLUWA bá pa á. Tamari, iyawo ọmọ Juda, bí ọmọ meji fún un: Peresi ati Sera. Àwọn ọmọ Peresi ni Hesironi ati Hamuli. Sera bí ọmọ marun-un: Simiri, Etani, Hemani, Kalikoli ati Dada. Kami ni baba Akani; Akani yìí ni ó kó wahala bá Israẹli, nítorí pé ó rú òfin nípa àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀. Etani ni ó bí Asaraya. Àwọn ọmọ Hesironi ni Jerameeli, Ramu ati Kelubai. Ramu bí Aminadabu, Aminadabu bi Naṣoni, olórí pataki ninu ẹ̀yà Juda, Nahiṣoni ni baba Salima; Salima ni ó bí Boasi, Boasi bí Obedi, Obedi sì bí Jese. Jese bí ọmọ meje; orúkọ wọn nìyí bí wọ́n ṣe tẹ̀lé ara wọn: Eliabu ni àkọ́bí, lẹ́yìn náà Abinadabu ati Ṣimea; Netaneli ati Radai; Osemu ati Dafidi. Àwọn arabinrin wọn ni Seruaya ati Abigaili. Seruaya yìí ló bí Abiṣai, Joabu ati Asaheli. Abigaili fẹ́ Jeteri láti inú ìran Iṣimaeli, ó sì bí Amasa fún un. Hesironi ni baba Kalebu. Asuba (ati Jeriotu) ni aya Kalebu yìí, Asuba bí ọmọkunrin mẹta fún un: Jeseri, Ṣobabu, ati Aridoni. Nígbà tí Asuba kú, Kalebu fẹ́ Efurati, Efurati sì bí Huri fún un. Huri ni ó bí Uri, Uri sì bí Besaleli. Nígbà tí Hesironi di ẹni ọgọta ọdún, ó fẹ́ ọmọbinrin Makiri, baba Gileadi. Ọmọbinrin yìí sì bí ọmọkunrin kan fún un tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Segubu. Segubu ni ó bí Jairi, tí ó jọba lórí ìlú ńláńlá mẹtalelogun ní ilẹ̀ Gileadi. Ṣugbọn Geṣuri ati Aramu gba Hafoti Jairi lọ́wọ́ rẹ̀, ati Kenati ati àwọn ìletò tí ó wà ní àyíká rẹ̀; gbogbo wọn jẹ́ ọgọta ìlú. Gbogbo wọn jẹ́ arọmọdọmọ Makiri, baba Gileadi. Lẹ́yìn ìgbà tí Hesironi kú, Kalebu ṣú Efurata, iyawo baba rẹ̀ lópó, ó sì bí Aṣuri, tíí ṣe baba Tekoa. Jerameeli, àkọ́bí Hesironi, bí ọmọkunrin marun-un: Ramu ni àkọ́bí, lẹ́yìn rẹ̀ ni wọ́n bí Buna, Oreni, Osemu, ati Ahija. Jerameeli tún ní aya mìíràn, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Atara, òun ni ìyá Onamu. Àwọn ọmọ Ramu, àkọ́bí Jerameeli ni: Maasi, Jamini ati Ekeri. Onamu bí ọmọ meji: Ṣamai ati Jada. Ṣamai náà bí ọmọ meji: Nadabu ati Abiṣuri. Orúkọ aya Abiṣuri ni Abihaili, ó sì bí Ahibani ati Molidi fún un. Nadabu, arakunrin Abiṣuri náà bí ọmọ meji: Seledi ati Apaimu; ṣugbọn Seledi kò bímọ títí tí ó fi kú. Apaimu ni baba Iṣi. Iṣi bí Ṣeṣani, Ṣeṣani sì bí Ahilai. Jada, arakunrin Ṣamai, bí ọmọ meji: Jeteri ati Jonatani, ṣugbọn Jeteri kò bímọ títí tí ó fi kú. Jonatani bí ọmọ meji: Peleti ati Sasa. Àwọn ni ìran Jerameeli. Ṣeṣani kò bí ọmọkunrin kankan, kìkì ọmọbinrin ni ó bí; ṣugbọn Ṣeṣani ní ẹrú kan, ará Ijipti, tí ń jẹ́ Jariha. Ṣeṣani fi ọmọ rẹ̀ obinrin fún Jariha, ẹrú rẹ̀, ó sì bí Atai fún ẹrú náà. Atai ni baba Natani, Natani sì ni baba Sabadi. Sabadi bí Efiali, Efiali sì bí Obedi. Obedi ni baba Jehu, Jehu sì ni baba Asaraya. Asaraya ni ó bí Helesi, Helesi ni ó sì bí Eleasa. Eleasa bí Sisimai, Sisimai bí Ṣalumu; Ṣalumu bí Jekamaya, Jekamaya sì bí Eliṣama. Àwọn ọmọ Kalebu, arakunrin Jerameeli, nìwọ̀nyí: Mareṣa, baba Sifi ni àkọ́bí rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó bí Heburoni. Heburoni bí ọmọ mẹrin: Kora, Tapua, Rekemu ati Ṣema. Ṣema bí Rahamu, Rahamu bí Jokeamu, Rekemu sì bí Ṣamai. Ṣamai ló bí Maoni, Maoni sì bí Betisuri. Kalebu tún ní obinrin kan tí ń jẹ́ Efa, ó bí ọmọ mẹta fún un: Harani, Mosa ati Gasesi. Harani bí ọmọ kan tí ń jẹ́ Gasesi. Àwọn ọmọ Jadai nìwọ̀nyí: Regemu, Jotamu, ati Geṣani, Peleti, Efa ati Ṣaafu. Kalebu tún ní obinrin mìíràn tí ń jẹ́ Maaka. Ó bí ọmọ meji fún un: Ṣeberi ati Tirihana. Maaka yìí kan náà ni ó bí Ṣaafu, baba Madimana, tí ó tẹ ìlú Madimana dó, ati Ṣefa, baba Makibena ati Gibea, àwọn ni wọ́n tẹ ìlú Makibena ati ìlú Gibea dó. Kalebu tún bí ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Akisa. Àwọn ìran Kalebu yòókù ni: àwọn ọmọ Huri àkọ́bí Efurata, iyawo Kalebu: ati Ṣobali, baba Kiriati Jearimu; Salima, baba Bẹtilẹhẹmu, ati Harefu baba Betigaderi. Ṣobali baba Kiriati Jearimu ni baba gbogbo àwọn ará Haroe, ati ìdajì àwọn tí ń gbé Menuhotu, Òun náà ni baba ńlá gbogbo àwọn ìdílé tí ń gbé Kiriati Jearimu, àwọn ìdílé bíi Itiri, Puti, Ṣumati, ati Miṣirai; lára wọn ni àwọn tí wọn ń gbé ìlú Sora ati Eṣitaolu ti ṣẹ̀. Salima ni baba àwọn ará Bẹtilẹhẹmu, Netofati, ati ti Atirotu Beti Joabu; àwọn ará Soriti ati ìdajì àwọn ará Manahati. Àwọn ìdílé àwọn akọ̀wé tí wọn ń gbé Jabesi nìyí: àwọn ará Tirati, Ṣimeati, ati Sukati. Àwọn ni ará Keni tí wọ́n ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Hamati baba ńlá wọn ní ilé Rekabu. Àwọn ọmọ Dafidi tí a bí fún un ní Heburoni nìwọ̀nyí, bí wọ́n ṣe tẹ̀lé ara wọn: Aminoni tí Ahinoamu ará Jesireeli bí fún un ni àkọ́bí rẹ̀, lẹ́yìn rẹ̀ ni Daniẹli, ọmọ Abigaili ará Kamẹli. Ẹkẹta ni Absalomu, ọmọ Maaka, ọmọbinrin Talimai, ọba ìlú Geṣuri; lẹ́yìn náà Adonija ọmọ Hagiti. Ẹkarun-un ni Ṣefataya, ọmọ Abitali; lẹ́yìn rẹ̀ ni Itireamu ọmọ Egila. Ní Heburoni, níbi tí Dafidi ti jọba fún ọdún meje ati ààbọ̀, ni wọ́n ti bí àwọn mẹfẹẹfa fún un. Lẹ́yìn náà, Dafidi jọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹtalelọgbọn. Àwọn ọmọ tí Dafidi bí ní Jerusalẹmu nìwọ̀nyí: Batiṣeba, ọmọbinrin Amieli, bí ọmọ mẹrin fún un: Ṣimea, Ṣobabu, Natani ati Solomoni. Àwọn ọmọ mẹsan-an mìíràn tí Dafidi tún bí ni: Ibihari, Eliṣua, ati Elipeleti; Noga, Nefegi, ati Jafia, Eliṣama, Eliada, ati Elifeleti, Dafidi ni ó bí gbogbo wọn, yàtọ̀ sí àwọn ọmọ tí àwọn obinrin mìíràn tún bí fún un. Ó bí ọmọbinrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tamari. Àwọn ọmọ Solomoni ọba nìwọ̀nyí: Rehoboamu, Abija, Asa, ati Jehoṣafati; Joramu, Ahasaya, ati Joaṣi; Amasaya, Asaraya, ati Jotamu; Ahasi, Hesekaya, ati Manase, Amoni ati Josaya. Orúkọ àwọn ọmọ Josaya mẹrẹẹrin, bí wọ́n ṣe tẹ̀lé ara wọn ni: Johanani, Jehoiakimu, Sedekaya ati Ṣalumu. Jehoiakimu bí ọmọ meji: Jekonaya ati Sedekaya. Àwọn ọmọ Jehoiakini, ọba tí a mú lẹ́rú lọ sí Babiloni nìwọ̀nyí: Ṣealitieli, Malikiramu, Pedaaya, ati Ṣenasari, Jekamaya, Hoṣama ati Nedabaya. Pedaaya bí ọmọ meji: Serubabeli, ati Ṣimei. Serubabeli bí ọmọ meji: Meṣulamu ati Hananaya, ati ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Ṣelomiti. Serubabeli tún bí ọmọ marun-un mìíràn: Haṣuba, Oheli, ati Berekaya; Hasadaya ati Juṣabi Hesedi. Hananaya bí ọmọ meji: Pelataya ati Jeṣaaya, àwọn ọmọ Refaaya, ati ti Arinoni, ati ti Ọbadaya, ati ti Ṣekanaya. Ṣekanaya ní ọmọ kan, tí ń jẹ́ Ṣemaaya. Ṣemaaya bí ọmọ marun-un: Hatuṣi, Igali, Baraya, Nearaya ati Ṣafati. Nearaya bí ọmọ mẹta: Elioenai, Hisikaya ati Asirikamu. Elioenai bí ọmọ meje: Hodafaya, Eliaṣibu, Pelaaya, Akubu, Johanani, Delaaya ati Anani. Àwọn ọmọ Juda ni: Peresi, Hesironi, Kami, Huri, ati Ṣobali. Ṣobali ni ó bí Reaaya. Reaaya sì bí Jahati. Jahati ni baba Ahumai ati Lahadi. Àwọn ni ìdílé àwọn tí ń gbé Sora. Àwọn ọmọ Etamu ni: Jesireeli, Iṣima, ati Idibaṣi. Orúkọ arabinrin wọn ni Haseleliponi. Penueli ni baba Gedori. Eseri bí Huṣa. Àwọn ni ọmọ Huri, àkọ́bí Efurata, tí ó jẹ́ baba Bẹtilẹhẹmu. Aṣuri, baba Tekoa, ní aya meji: Hela ati Naara. Naara bí ọmọ mẹrin fún un: Ahusamu, Heferi, Temeni, ati Haahaṣitari. Hela bí ọmọ mẹta fún un: Sereti, Iṣari, ati Etinani. Kosi ni baba Anubi ati Sobeba. Òun ni baba ńlá àwọn ìdílé Ahaheli, ọmọ Harumu. Ọkunrin kan, tí à ń pè ní Jabesi, jẹ́ eniyan pataki ju àwọn arakunrin rẹ̀ lọ. Ìyá rẹ̀ sọ ọ́ ní orúkọ yìí nítorí ìrora pupọ tí ó ní nígbà tí ó bí i. Jabesi gbadura sí Ọlọrun Israẹli pé, “Ọlọrun jọ̀wọ́ bukun mi, sì jẹ́ kí ilẹ̀ ìní mi pọ̀ sí i. Wà pẹlu mi, pa mí mọ́ kúrò ninu ewu, má jẹ́ kí jamba ṣe mí!” Ọlọrun sì ṣe ohun tí ó fẹ́ fún un. Kelubu, arakunrin Ṣuha, ni baba Mehiri, Mehiri ni baba Eṣitoni. Eṣitoni yìí ni ó bí Betirafa, Pasea ati Tẹhina. Tẹhina sì ni baba Irinahaṣi. Àwọn ni wọ́n ń gbé Reka. Kenasi bí ọmọ meji: Otinieli ati Seraaya. Otinieli náà bí Hatati ati Meonotai. Meonotai ni baba Ofira. Seraaya sì ni baba Joabu, baba àwọn ará Geharaṣimu, ìlú àwọn oníṣọ̀nà. Àwọn ni wọ́n tẹ gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ dó. Kalebu, ọmọ Jefune, bí ọmọ mẹta: Iru, Ela, ati Naamu. Ela ni ó bí Kenasi. Jehaleli sì ni baba Sifi, Sifa, Tiria, ati Asareli. Ẹsira bí Jeteri, Meredi, Eferi, ati Jaloni. Meredi fẹ́ Bitia, ọmọbinrin Farao. Wọ́n bí ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Miriamu ati ọmọkunrin meji: Ṣamai ati Iṣiba. Iṣiba ni baba Eṣitemoa. Meredi tún ní iyawo mìíràn, òun jẹ́ ará Juda, ó bí ọmọkunrin mẹta fún un: Jeredi, baba Gedori, Heberi baba Soko, ati Jekutieli, baba Sanoa. Hodia fẹ́ arabinrin Nahamu, àwọn ọmọ wọn ni wọ́n ṣẹ ẹ̀yà Garimi, tí wọn ń gbé ìlú Keila sílẹ̀, ati àwọn ìran Maakati tí wọn ń gbé ìlú Eṣitemoa. Simoni ni baba Aminoni, Rina, Benhanani ati Tiloni. Iṣi sì ni baba Soheti ati Benisoheti. Ṣela, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Juda, ni baba Eri, baba Leka. Laada ni baba Mareṣa, ati ìdílé àwọn tí wọ́n ń hun aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ funfun ní Beti Aṣibea ati Jokimu, ati àwọn ará ìlú Koseba, Joaṣi ati Sarafu, tí wọ́n fi ìgbà kan jẹ́ alákòóso ní Moabu, tí wọ́n sì pada sí Bẹtilẹhẹmu. (Àkọsílẹ̀ yìí jẹ́ ti àtijọ́.) Wọ́n jẹ́ amọ̀kòkò ní ààfin ọba, wọ́n sì ń gbé ìlú Netaimu ati Gedera. Simeoni ni baba Nemueli, Jamini, Jaribu, Sera, ati Ṣaulu. Ṣaulu bí Ṣalumu, Ṣalumu bí Mibisamu, Mibisamu sì bí Miṣima. Àwọn ọmọ Miṣima nìyí: Hamueli, Sakuri, ati Ṣimei. Ṣimei bí ọmọkunrin mẹrindinlogun ati ọmọbinrin mẹfa. Ṣugbọn àwọn arakunrin rẹ̀ kò bí ọmọ pupọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yà rẹ̀ kò pọ̀ bí ẹ̀yà Juda. Àwọn ìran Simeoni ní ń gbé àwọn ìlú wọnyi títí di àkókò ọba Dafidi: Beeriṣeba, Molada, ati Hasariṣuali. Biliha, Esemu, ati Toladi; Betueli, Horima, ati Sikilagi; Beti Makabotu, Hasasusimu, Betibiri, ati Ṣaaraimu. Àwọn ìletò wọn ni: Etamu, Aini, Rimoni, Tokeni ati Aṣani, àwọn ìlú marun-un pẹlu àwọn ìgbèríko tí ó yí wọn ká títí dé ìlú Baali. Àwọn agbègbè náà ni wọ́n ń gbé, wọ́n sì ní àkọsílẹ̀ ìdílé wọn. Meṣobabu, Jamileki, ati Joṣa, jẹ́ ọmọ Amasaya; Joẹli, ati Jehu, ọmọ Joṣibaya, ọmọ Seraaya, ọmọ Asieli. Elioenai, Jaakoba, ati Jeṣohaya; Asaya, Adieli, Jesimieli ati Bẹnaya; Sisa, ọmọ Ṣifi, ọmọ Aloni, ọmọ Jedaaya, ọmọ Ṣimiri, ọmọ Ṣemaaya. Gbogbo wọn jẹ́ olórí ní ìdílé wọn, ìdílé àwọn baba wọn sì pọ̀ lọpọlọpọ. Wọ́n rìn títí dé ẹnubodè Gedori, ní apá ìlà oòrùn àfonífojì, láti wá koríko fún àwọn ẹran ọ̀sìn wọn. Níbẹ̀ ni wọ́n ti rí ilẹ̀ tí ó ní koríko, tí ó sì dára fún àwọn ẹran wọn. Ilẹ̀ náà tẹ́jú, ó parọ́rọ́, alaafia sì wà níbẹ̀; àwọn ọmọ Hamu ni wọ́n ti ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí. Nígbà tí Hesekaya, ọba Juda wà lórí oyè, àwọn tí a ti dárúkọ wọnyi lọ sí Meuni, wọ́n ba àgọ́ àwọn tí wọn ń gbé ibẹ̀ jẹ́, wọ́n pa wọ́n run títí di òní, wọ́n sì sọ ibẹ̀ di ilẹ̀ tiwọn, nítorí pé koríko tútù pọ̀ níbẹ̀ fún àwọn ẹran ọ̀sìn wọn. Ẹẹdẹgbẹta (500) ninu àwọn eniyan Simeoni ló lọ sí òkè Seiri; àwọn olórí wọn ni: Pelataya, Nearaya, Refaaya, ati Usieli, lára àwọn ọmọ Iṣi. Wọ́n pa àwọn ọmọ Amaleki yòókù tí wọ́n sá àsálà, wọ́n sì ń gbé orí ilẹ̀ wọn títí di òní olónìí. Reubẹni ni àkọ́bí Jakọbu, (Ṣugbọn nítorí pé Reubẹni fẹ́ ọ̀kan ninu àwọn obinrin baba rẹ̀, baba rẹ̀ gba ipò àgbà lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì gbé e fún àwọn ọmọ Josẹfu. Ninu àkọsílẹ̀ ìdílé, a kò kọ orúkọ rẹ̀ sí ipò àkọ́bí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yà Juda di ẹ̀yà tí ó lágbára ju gbogbo ẹ̀yà yòókù lọ, tí wọ́n sì ń jọba lórí wọn, sibẹsibẹ ipò àkọ́bí jẹ́ ti àwọn ọmọ Josẹfu). Àwọn ọmọ Reubẹni, àkọ́bí Jakọbu, ni: Hanoku, Palu, Hesironi ati Kami. Joẹli ni ó bí Ṣemaya, Ṣemaya bí Gogu, Gogu bí Ṣimei; Ṣimei bí Mika, Mika bí Reaaya, Reaaya bí Baali; Baali bí Beera, tí Tigilati Pileseri ọba Asiria mú lẹ́rú lọ; Beera yìí jẹ́ olórí ninu ẹ̀yà Reubẹni. Àwọn arakunrin rẹ̀ ní ìdílé wọn, nígbà tí a kọ àkọsílẹ̀, ìran wọn nìyí: olórí wọn ni Jeieli, ati Sakaraya, ati Bela, ọmọ Asasi, ọmọ Ṣema, ọmọ Joẹli, tí wọn ń gbé Aroeri títí dé Nebo ati Baali Meoni. Ilẹ̀ wọn lọ ní apá ìlà oòrùn títí dé àtiwọ aṣálẹ̀, ati títí dé odò Yufurate, nítorí pé ẹran ọ̀sìn wọn pọ̀ ní ilẹ̀ Gileadi. Ní àkókò ọba Saulu, àwọn ẹ̀yà Reubẹni wọnyi gbógun ti àwọn ará Hagiriti, wọ́n pa wọ́n run, wọ́n gba ilẹ̀ wọn tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn Gileadi. Àwọn ẹ̀yà Gadi ń gbé òdìkejì ẹ̀yà Reubẹni ní ilẹ̀ Baṣani, títí dé Saleka: Joẹli ni olórí wọn ní ilẹ̀ Baṣani, Safamu ni igbá keji rẹ̀; àwọn olórí yòókù ni Janai ati Ṣafati. Àwọn arakunrin wọn ní ìdílé wọn ni: Mikaeli, Meṣulamu, ati Ṣeba; Jorai, Jakani, Sia, ati Eberi, gbogbo wọn jẹ́ meje. Àwọn ni ọmọ Abihaili, ọmọ Huri, ọmọ Jaroa, ọmọ Gileadi, ọmọ Mikaeli, ọmọ Jeṣiṣai, ọmọ Jahido, ọmọ Busi. Ahi, ọmọ Abidieli, ọmọ Guni ni olórí ìdílé baba wọn; wọ́n ń gbé Gileadi, Baṣani ati àwọn ìlú tí wọ́n yí Baṣani ká, ati ní gbogbo ilẹ̀ pápá Ṣaroni. A kọ àkọsílẹ̀ wọn ní àkókò Jotamu, ọba Juda, ati ní àkókò Jeroboamu ọba Israẹli. Àwọn ẹ̀yà Reubẹni, àwọn ẹ̀yà Gadi, ati ìdajì ẹ̀yà Manase, ní ẹgbaa mejilelogun ati ẹẹdẹgbẹrin ó lé ọgọta (44,760) akọni ọmọ ogun tí wọ́n ń lo asà, idà, ọfà ati ọrun lójú ogun, tí wọ́n gbáradì fún ogun. Wọ́n gbógun ti àwọn ará Hagiriti, Jeturi, Nafiṣi ati Nodabu. Nígbà tí wọ́n rí ìrànlọ́wọ́ gbà, wọ́n ṣẹgun àwọn ará Hagiriti ati àwọn tí wọ́n wà pẹlu wọn, nítorí wọ́n ké pe Ọlọrun lójú ogun náà, ó sì gbọ́ igbe wọn nítorí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e. Àwọn ẹran ọ̀sìn tí wọ́n kó lójú ogun nìwọ̀nyí: ẹgbaa mẹẹdọgbọn (50,000) ràkúnmí, ọ̀kẹ́ mejila lé ẹgbaarun (250,000) aguntan, ati ẹgbaa (2,000) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́; wọ́n sì kó ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) ọkunrin lẹ́rú. Ọpọlọpọ eniyan ni wọ́n pa, nítorí pé Ọlọrun ni ó jà fún wọn; wọ́n sì ń gbé ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn títí tí àwọn ará Asiria fi kó wọn lẹ́rú. Ìdajì ẹ̀yà Manase ń gbé Baṣani, wọ́n pọ̀ pupọ; wọ́n tàn ká títí dé Baali Herimoni, Seniri, ati òkè Herimoni. Àwọn Olórí ìdílé wọn nìwọ̀nyí: Eferi, Iṣi, Elieli, ati Asirieli; Jeremaya, Hodafaya ati Jahidieli, akikanju jagunjagun ni wọ́n, wọ́n sì jẹ́ olókìkí ati olórí ní ilé baba wọn. Ṣugbọn àwọn ẹ̀yà náà ṣẹ Ọlọrun baba wọn, wọ́n pada lẹ́yìn rẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bọ àwọn oriṣa tí àwọn tí Ọlọrun parun nítorí wọn ń bọ. Nítorí náà, Ọlọrun ta Pulu ọba Asiria ati Tigilati Pileseri ọba Asiria, nídìí láti gbógun ti ilẹ̀ náà; wọ́n bá kó àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ati ti Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase tí wọn ń gbé ìhà ìlà oòrùn lẹ́rú lọ sí ilẹ̀ Hala, Habori, Hara, ati ẹ̀bá odò Gosani títí di òní olónìí. Àwọn ọmọ Lefi nìwọ̀nyí: Geṣomu, Kohati ati Merari. Kohati bí ọmọkunrin mẹrin: Amramu, Iṣari, Heburoni ati Usieli. Amramu bí ọmọ mẹta: Aaroni, Mose, ati ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Miriamu. Aaroni bí ọmọkunrin mẹrin: Nadabu, Abihu, Eleasari ati Itamari. Ìran Eleasari ati àwọn arọmọdọmọ rẹ̀ nìwọ̀nyí: Eleasari ni baba Finehasi, Finehasi ni ó bí Abiṣua; Abiṣua bí Buki, Buki sì bí Usi. Usi ni baba Serahaya, Serahaya ló bí Meraiotu, Meraiotu bí Amaraya, Amaraya sì bí Ahitubu. Ahitubu ni baba Sadoku, Sadoku bí Ahimaasi, Ahimaasi bí Asaraya, Asaraya sì bí Johanani. Johanani bí Asaraya (òun ni alufaa tí ó wà ninu tẹmpili tí Solomoni kọ́ sí Jerusalẹmu). Asaraya ni baba Amaraya, Amaraya ni ó bí Ahitubu; Ahitubu bí Sadoku, Sadoku sì bí Ṣalumu. Ṣalumu ni baba Hilikaya; Hilikaya bí Asaraya, Asaraya bí Seraaya; Seraaya sì bí Jehosadaki. Jehosadaki lọ sí ìgbèkùn nígbà tí Ọlọrun jẹ́ kí Nebukadinesari wá kó Juda ati Jerusalẹmu lọ sí ìgbèkùn. Àwọn ọmọ Lefi ni: Geriṣoni, Kohati ati Merari. Àwọn ọmọ Geriṣoni ni: Libini ati Ṣimei. Àwọn ọmọ Kohati ni: Amramu, Iṣari, Heburoni, ati Usieli. Àwọn ọmọ Merari ni: Mahili ati Muṣi. Àwọn ni baba ńlá àwọn ọmọ Lefi. Àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Geriṣoni nìwọ̀nyí: Libini ni baba Jahati, Jahati bí Sima, Sima bí Joa, Joa bí Ido, Ido bí Sera, Sera sì bí, Jeaterai. Àwọn tí ó ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Kohati nìwọ̀nyí: Aminadabu ni baba Kora, Kora ló bí Asiri; Asiri bí Elikana, Elikana bí Ebiasafu, Ebiasafu sì bí Asiri. Asiri ni baba Tahati, Tahati ló bí Urieli, Urieli bí Usaya, Usaya sì bí Saulu. Ọmọ meji ni Elikana bí: Amasai ati Ahimotu. Àwọn ọmọ Ahimotu nìwọ̀nyí: Elikana ni baba Sofai, Sofai ni ó bí Nahati; Nahati bí Eliabu, Eliabu bí Jerohamu, Jerohamu sì bí Elikana. Samuẹli bí ọmọkunrin meji: Joẹli ni àkọ́bí, Abija sì ni ikeji. Àwọn ọmọ Merari nìwọ̀nyí: Mahili ni baba Libini, Libini bí Ṣimei, Ṣimei bí Usali, Usali bí Ṣimea, Ṣimea bí Hagaya, Hagaya sì bí Asaya. Dafidi fi àwọn wọnyi ṣe alákòóso ẹgbẹ́ akọrin ninu ilé OLUWA lẹ́yìn tí wọn ti gbé Àpótí Majẹmu OLUWA sibẹ; àwọn ni wọ́n ń kọ orin ninu Àgọ́ Àjọ títí tí Solomoni fi kọ́ ilé OLUWA parí ní Jerusalẹmu; àṣegbà ni wọ́n ń ṣiṣẹ́ wọn. Àwọn tí wọ́n ṣiṣẹ́ náà, pẹlu àwọn ọmọ wọn nìwọ̀nyí: Ninu ìdílé Kohati: Hemani, akọrin, ọmọ Joẹli, ọmọ Samuẹli, ọmọ Elikana, ọmọ Jerohamu, ọmọ Elieli, ọmọ Toa, ọmọ Sufu, ọmọ Elikana, ọmọ Mahati, ọmọ Amasai, ọmọ Elikana, ọmọ Joẹli, ọmọ Asaraya, ọmọ Sefanaya, ọmọ Tahati, ọmọ Asiri, ọmọ Ebiasafu, ọmọ Kora, ọmọ Iṣari, ọmọ Kohati, ọmọ Lefi, ọmọ Israẹli. Asafu, arakunrin rẹ̀, ni olórí àwọn ẹgbẹ́ akọrin tí ń dúró ní apá ọ̀tun rẹ̀. Asafu yìí jẹ́ ọmọ Berekaya, ọmọ Ṣimea; Ọmọ Mikaeli, ọmọ Baaseaya, ọmọ Malikija, ọmọ Etini, ọmọ Sera, ọmọ Adaya; ọmọ Etani, ọmọ Sima, ọmọ Ṣimei, ọmọ Jahati, ọmọ Geriṣomu, ọmọ Lefi. Etani arakunrin wọn láti inú ìdílé Merari ni olórí àwọn ẹgbẹ́ akọrin tí ń dúró ní apá òsì rẹ̀. Ìran Etani títí lọ kan Lefi nìyí: ọmọ Kiṣi ni Etani, ọmọ Abidi, ọmọ Maluki; ọmọ Haṣabaya, ọmọ Amasaya, ọmọ Hilikaya; ọmọ Amisi, ọmọ Bani, ọmọ Ṣemeri; ọmọ Mahili, ọmọ Muṣi, ọmọ Merari, ọmọ Lefi. Wọ́n yan àwọn ọmọ Lefi, arakunrin wọn yòókù láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ mìíràn tí ó kù ninu ilé Ọlọrun. Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni wọ́n máa ń rúbọ lórí pẹpẹ ẹbọ sísun ati lórí pẹpẹ turari; àwọn ni wọ́n máa ń ṣe gbogbo iṣẹ́ ìsìn ninu ibi mímọ́ jùlọ, tí wọ́n sì máa ń ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Mose, iranṣẹ Ọlọrun là sílẹ̀. Àwọn ọmọ Aaroni nìwọ̀nyí: Eleasari baba Finehasi, baba Abiṣua; baba Buki, baba Usi, baba Serahaya; baba Meraiotu, baba Amaraya, baba Ahitubu; baba Sadoku, baba Ahimaasi. Ilẹ̀ tí a pín fún ìran Aaroni nìyí, pẹlu ààlà wọn: ìdílé Kohati ni a kọ́kọ́ pín ilẹ̀ fún ninu àwọn ọmọ Lefi. Wọ́n fún wọn ní ìlú Heburoni ní ilẹ̀ Juda, ati gbogbo ilẹ̀ pápá oko tí ó yí i ká, ṣugbọn Kalebu ọmọ Jefune ni wọ́n fún ní ìgbèríko ati ìletò tí ó yí ìlú Heburoni ká. Àwọn ọmọ Aaroni ni a pín àwọn ìlú ààbò wọnyi fún: Heburoni, Libina, Jatiri ati Eṣitemoa, pẹlu àwọn pápá oko tí ó yí wọn ká. Bẹ́ẹ̀ náà ni Hileni, ati Debiri, ati Aṣani ati Beti Ṣemeṣi pẹlu pápá oko tí ó yí wọn ká. Àwọn ìlú tí wọ́n pín fún wọn, ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Bẹnjamini nìwọ̀nyí: Geba, Alemeti, ati Anatoti, pẹlu pápá oko tí ó yí wọn ká. Gbogbo àwọn ìlú tí ó jẹ́ tiwọn ní gbogbo ìdílé wọn jẹ́ mẹtala. Gègé ni wọ́n ṣẹ́ lórí ìlú mẹ́wàá ara ilẹ̀ ìdajì ẹ̀yà Manase tí ó wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, tí wọn sì pín wọn fún àwọn ìdílé Kohati tí ó kù. Ìlú mẹtala ni wọ́n pín fún àwọn ọmọ Geriṣomu ní ìdílé ìdílé lára àwọn ìlú ẹ̀yà Isakari, Aṣeri, Nafutali, ati ìdajì ẹ̀yà Manase, tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Baṣani. Ìlú mejila ni wọ́n pín fún àwọn ọmọ Merari ní ìdílé ìdílé, lára àwọn ìlú ẹ̀yà Reubẹni, Gadi ati ti Sebuluni. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli ṣe fún àwọn ọmọ Lefi ní gbogbo àwọn ìlú ńláńlá pẹlu àwọn pápá oko tí ó yí wọn ká. Wọ́n tún ṣẹ́ gègé láti fún wọn ní àwọn ìlú ńláńlá tí a dárúkọ wọnyi lára ìlú àwọn ẹ̀yà Juda, Simeoni ati ti Bẹnjamini. Lára ilẹ̀ ẹ̀yà Efuraimu ni wọ́n ti pín àwọn ìlú ńláńlá fún àwọn ìdílé kan ninu àwọn ọmọ Kohati. Àwọn ìlú ààbò tí wọ́n fún wọn, pẹlu àwọn pápá oko tí ó yí wọn ká, ní agbègbè olókè Efuraimu nìwọ̀nyí; Ṣekemu, ati Geseri; Jokimeamu ati Beti Horoni; Aijaloni ati Gati Rimoni. Ninu ilẹ̀ ìdajì ẹ̀yà Manase tí ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn, wọ́n fún ìdílé àwọn ọmọ Kohati tí ó kù ní Aneri ati Bileamu, pẹlu àwọn pápá oko tí ó yí wọn ká. Ninu ilẹ̀ ìdajì ẹ̀yà Manase tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, wọ́n fún àwọn ọmọ Geriṣoni ní ìlú wọnyi, pẹlu àwọn pápá oko tí ó yí wọn ká: Golani ní ilẹ̀ Baṣani, ati Aṣitarotu. Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Isakari; wọ́n fún wọn ní Kedeṣi ati Daberati; Ramoti ati Anemu, pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn. Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Aṣeri, wọ́n fún wọn ní Maṣali ati Abidoni; Hukoku ati Rehobu, pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn. Lára ilẹ̀ ẹ̀yà Nafutali, wọ́n fún wọn ní Kedeṣi ní ilẹ̀ Galili, Hamoni, ati Kiriataimu, pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn. Wọ́n pín àwọn ìlú wọnyi fún àwọn ìdílé tí ó kù ninu àwọn ọmọ Merari. Lára ilẹ̀ ẹ̀yà Sebuluni, wọ́n fún wọn ní Rimono ati Tabori, pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn. Lára ilẹ̀ ẹ̀yà Reubẹni tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, ní ìkọjá Jọdani níwájú Jẹriko, wọ́n fún wọn ní Beseri tí ó wà ní ara òkè, ati Jahasa, Kedemotu ati Mefaati pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn. Lára ilẹ̀ ẹ̀yà Gadi, wọ́n fún wọn ní Ramoti ní ilẹ̀ Gileadi ati Mahanaimu, Heṣiboni ati Jaseri, pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn. Àwọn mẹrin ni ọmọ Isakari: Tola, Pua, Jaṣubu ati Ṣimironi. Àwọn ọmọ Tola ni: Usi, Refaaya, Jerieli, Jahimai, Ibisamu ati Ṣemueli, àwọn ni baálé ninu ìdílé Tola, baba wọn, akikanju jagunjagun ni wọ́n ní àkókò wọn. Ní ayé Dafidi ọba, àwọn akikanju jagunjagun wọnyi jẹ́ ẹgbaa mọkanla ó lé ẹgbẹta (22,600). Usi ni ó bí Isiraya. Isiraya sì bí ọmọ mẹrin: Mikaeli, Ọbadaya, Joẹli, ati Iṣaya; wọ́n di marun-un, àwọn maraarun ni wọ́n sì jẹ́ ìjòyè. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ìran wọn ní ìdílé ìdílé, àwọn jagunjagun tí wọ́n ní tó ẹgbaa mejidinlogun (36,000) kún ara wọn, ní ìsọ̀rí ìsọ̀rí; nítorí wọ́n ní ọpọlọpọ iyawo ati ọmọ. Gbogbo àwọn akikanju jagunjagun tí a kọ orúkọ wọn sílẹ̀ ninu àwọn ìbátan wọn ninu ẹ̀yà Isakari jẹ́ ẹgbaa mẹtalelogoji ó lé ẹgbẹrun (87,000). Àwọn mẹta ni ọmọ Bẹnjamini: Bela, Bekeri, ati Jediaeli. Bela bí ọmọ marun-un: Esiboni, Usi, Usieli, Jerimotu ati Iri. Àwọn ni baálé ìdílé wọn, wọ́n sì jẹ́ akọni jagunjagun. Gbogbo àwọn akikanju jagunjagun tí a kọ orúkọ wọn sílẹ̀ ninu ìdílé wọn jẹ́ ẹgbaa mọkanla ati mẹrinlelọgbọn (22,034). Bekeri bí ọmọ mẹsan-an: Semira, Joaṣi, ati Elieseri; Elioenai, Omiri, ati Jeremotu; Abija, Anatoti, ati Alemeti. Àkọsílẹ̀ ìran wọn ní ìdílé, àwọn baálé baálé ní ilé baba wọn, tí wọ́n jẹ́ akọni jagunjagun, gbogbo wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati igba (20,200). Jediaeli ni baba Bilihani; Bilihani bí ọmọ meje: Jeuṣi, Bẹnjamini, Ehudu, Kenaana, Setani, Taṣiṣi ati Ahiṣahari. Gbogbo wọn jẹ́ ọmọ Jediaeli; àwọn tí wọ́n jẹ́ baálé baálé ní ilé baba wọn ati akọni jagunjagun ninu ìran wọn tó ẹẹdẹgbaasan-an ó lé igba (17,200). Ṣupimu ati Hupimu jẹ́ ọmọ Iri, ọmọ Aheri sì ni Huṣimu. Nafutali bí ọmọ mẹrin: Jasieli, Guni, Jeseri, ati Ṣalumu. Biliha ni ìyá baba wọn. Manase fẹ́ obinrin kan, ará Aramea; ọmọ meji ni obinrin náà bí fún un; Asirieli, ati Makiri, baba Gileadi. Makiri fẹ́ iyawo kan ará Hupi, ati ọ̀kan ará Ṣupimu. Orúkọ arabinrin rẹ̀ ni Maaka. Orúkọ ọmọ rẹ̀ keji ni Selofehadi; tí gbogbo ọmọ tirẹ̀ jẹ́ kìkì obinrin. Maaka, Iyawo Makiri, bí ọmọ meji: Pereṣi ati Ṣereṣi. Ṣereṣi ni ó bí Ulamu ati Rakemu; Ulamu sì bí Bedani. Àwọn ni ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manase. Arabinrin Gileadi kan tí ń jẹ́ Hamoleketu ni ó bí Iṣodu, Abieseri, ati Mahila. Ṣemida bí ọmọkunrin mẹrin: Ahiani, Ṣekemu, Liki, ati Aniamu. Àwọn arọmọdọmọ Efuraimu nìwọ̀nyí: Ṣutela ni baba Beredi, baba Tahati, baba Eleada, baba Tahati, baba Sabadi, baba Ṣutela, Eseri, ati Eleadi; Eseri ati Eleadi yìí ni àwọn ará ìlú Gati pa nígbà tí wọ́n lọ kó ẹran ọ̀sìn àwọn ará Gati. Baba wọn, Efuraimu, ṣọ̀fọ̀ wọn fún ọpọlọpọ ọjọ́. Àwọn arakunrin rẹ̀ bá wá láti tù ú ninu. Lẹ́yìn náà, Efuraimu bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan. Ó sọ ọmọ náà ní Beraya nítorí ibi tí ó dé bá ìdílé wọn. Efuraimu ní ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Ṣeera, òun ló kọ́ ìlú Beti Horoni ti òkè ati ti ìsàlẹ̀, ati Useni Ṣeera. Orúkọ àwọn ọmọ ati arọmọdọmọ Efuraimu yòókù ni Refa, baba Reṣefu, baba Tela, baba Tahani; baba Ladani, baba Amihudu, baba Eliṣama; baba Nuni, baba Joṣua. Àwọn ilẹ̀ ìní wọn ati àwọn agbègbè tí wọ́n tẹ̀dó sí nìwọ̀nyí: Bẹtẹli, Naarani ní apá ìlà oòrùn, Geseri ní apá ìwọ̀ oòrùn, Ṣekemu ati Aya; pẹlu àwọn ìletò tí ó wà lẹ́bàá àyíká wọn. Àwọn ìlú wọnyi wà lẹ́bàá ààlà ilẹ̀ àwọn ará Manase: Beti Ṣani, Taanaki, Megido, Dori ati gbogbo ìlú tí ó yí wọn ká. Níbẹ̀ ni àwọn ìran Josẹfu, ọmọ Jakọbu ń gbé. Àwọn ọmọ Aṣeri nìwọ̀nyí: Imina, Iṣifa, Iṣifi ati Beraya, ati ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Sera. Beraya bí ọmọkunrin meji: Heberi ati Malikieli, baba Birisaiti. Heberi bí ọmọkunrin mẹta: Jafileti, Ṣomeri ati Hotamu; ati ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Ṣua. Jafileti bí ọmọ mẹta: Pasaki, Bimihali, ati Aṣifatu. Ṣomeri, arakunrin Jafileti, bí ọmọkunrin mẹta: Roga, Jehuba ati Aramu. Hotamu, arakunrin rẹ̀, bí ọmọkunrin mẹrin: Sofa, Imina, Ṣeleṣi ati Amali. Sofa bí Ṣua, Haneferi, ati Ṣuali; Beri, ati Imira; Beseri, Hodi, ati Ṣama, Ṣiliṣa, Itirani, ati Beera. Jeteri bí: Jefune, Pisipa, ati Ara. Ula bí: Ara, Hanieli ati Risia. Àwọn ni ìran Aṣeri, wọ́n jẹ́ baálé baálé ni ìdílé baba wọn, àṣàyàn akọni jagunjagun, ati olórí láàrin àwọn ìjòyè. Àkọsílẹ̀ iye àwọn tí wọ́n tó ogun jà ninu wọn, ní ìdílé ìdílé jẹ́ ẹgbaa mẹtala (26,000). Bẹnjamini bí ọmọkunrin marun-un, Bela ni àkọ́bí, lẹ́yìn rẹ̀ ni Aṣibeli, lẹ́yìn rẹ̀, Ahara, lẹ́yìn rẹ̀, Nohahi, àbíkẹ́yìn rẹ̀ ni, Rafa. Àwọn ọmọ Bela ni: Adari, Gera, ati Abihudi, Abiṣua, Naamani, ati Ahoa, Gera, Ṣefufani, ati Huramu. Àwọn wọnyi ni ìran Ehudu: (Àwọn baálé baálé ninu ìran Geba, tí wọ́n kó lẹ́rú lọ sí ìlú Manahati): Naamani, Ahija ati Gera, tí ń jẹ́ Hegilamu, baba Usa, ati Ahihudu. Lẹ́yìn tí Ṣaharaimu ti kọ àwọn iyawo rẹ̀ mejeeji, Huṣimu ati Baara sílẹ̀, ó fẹ́ Hodeṣi, ó sì bímọ ní ilẹ̀ Moabu. Ọmọ meje ni Hodeṣi bí fún un: Jobabu, Sibia, Meṣa, ati Malikami, Jeusi, Sakia ati Mirima. Gbogbo wọn jẹ́ baálé baálé ní ìdílé wọn. Huṣimu náà bí ọmọkunrin meji fún un: Abitubu ati Elipaali. Elipaali bí ọmọkunrin mẹta: Eberi, Miṣamu ati Ṣemedi. Ṣemedi yìí ni ó kọ́ àwọn ìlú Ono, Lodi, ati gbogbo àwọn ìletò tí ó yí wọn ká. Beraya ati Ṣema ni olórí àwọn ìdílé tí wọn ń gbé ìlú Aijaloni, àwọn sì ni wọ́n lé àwọn tí wọn ń gbé ìlú Gati tẹ́lẹ̀ kúrò; àwọn ọmọ Beraya ni: Ahio, Ṣaṣaki, ati Jeremotu, Sebadaya, Aradi, ati Ederi, Mikaeli, Iṣipa ati Joha. Àwọn ọmọ Elipaali ni: Sebadaya, Meṣulamu, Hiṣiki, ati Heberi, Iṣimerai, Isilaya ati Jobabu. Àwọn ọmọ Ṣimei ni: Jakimu, Sikiri, ati Sabidi; Elienai, Siletai, ati Elieli; Adaaya, Beraaya ati Ṣimirati; Àwọn ọmọ Ṣaṣaki nìwọ̀nyí: Iṣipani, Eberi, ati Elieli; Abidoni, Sikiri, ati Hanani; Hananaya, Elamu, ati Antotija; Ifideaya ati Penueli. Àwọn ọmọ Jerohamu ni: Ṣamṣerai, Ṣeharaya, ati Atalaya; Jaareṣaya, Elija ati Sikiri. Àwọn ni baálé baálé ní ìdílé wọn, ìjòyè ni wọ́n ní ìran wọn; wọ́n ń gbé Jerusalẹmu. Jeieli, baba Gibeoni, ń gbé ìlú Gibeoni, Maaka ni orúkọ iyawo rẹ̀. Abidoni ni àkọ́bí rẹ̀, lẹ́yìn rẹ̀ ni ó bí: Suri, Kiṣi, Baali, ati Nadabu; Gedori, Ahio, Sekeri, ati Mikilotu (baba Ṣimea). Wọ́n ń bá àwọn arakunrin wọn gbé, àdúgbò wọn kọjú sí ara wọn ní Jerusalẹmu. Neri ni baba Kiṣi, Kiṣi ni ó bí Saulu, Saulu sì bí àwọn ọmọkunrin mẹrin: Jonatani, Malikiṣua, Abinadabu, ati Eṣibaali. Jonatani bí Meribibaali, Meribibaali sì bí Mika. Mika bí ọmọkunrin mẹrin: Pitoni, Meleki, Tarea ati Ahasi. Ahasi ni baba Jehoada. Jehoada sì ni baba: Alemeti, Asimafeti, ati Simiri. Simiri ni ó bí Mosa. Mosa bí Binea; Binea bí Rafa, Rafa bí Eleasa, Eleasa sì bí Aseli. Aseli bí ọmọkunrin mẹfa: Asirikamu, Bokeru, Iṣimaeli, Ṣearaya, Ọbadaya, ati Hanani. Aseli ni baba gbogbo wọn. Eṣeki, arakunrin Aseli, bí ọmọ mẹta: Ulamu ni àkọ́bí rẹ̀, lẹ́yìn náà Jeuṣi, lẹ́yìn náà Elifeleti. Àwọn ọmọ Ulamu jẹ́ jagunjagun, tafàtafà ni wọ́n, wọ́n sì lókìkí. Àwọn ọmọ ati ọmọ ọmọ rẹ̀ pọ̀. Aadọjọ ni wọ́n, ara ẹ̀yà Bẹnjamini sì ni gbogbo wọ́n. A kọ orúkọ àwọn ọmọ Israẹli sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìran wọn; a kọ wọ́n sinu ìwé Àwọn Ọba Israẹli. A kó àwọn ẹ̀yà Juda ní ìgbèkùn lọ sí Babiloni nítorí pé wọ́n ṣe alaiṣootọ sí Ọlọrun. Àwọn tí wọ́n kọ́kọ́ pada dé sórí ilẹ̀ wọn, ní ìlú wọn, ni àwọn ọmọ Israẹli, àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn òṣìṣẹ́ inú tẹmpili. Àwọn eniyan tí wọ́n wá láti inú ẹ̀yà Juda, Bẹnjamini, Efuraimu, ati Manase tí wọn ń gbé Jerusalẹmu nìwọ̀nyí: Utai ọmọ Amihudu, ọmọ Omiri, ọmọ Imiri, ọmọ Bani, ọ̀kan lára àwọn ọmọ Pẹrẹsi, ọmọ Juda. Àwọn ọmọ Ṣilo ni Asaaya, àkọ́bí rẹ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀. Àwọn ọmọ ti Sera ni Jeueli ati àwọn ìbátan rẹ̀, wọ́n jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó dín mẹ́wàá (690). Àwọn tí wọ́n wá láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini ni: Salu, ọmọ Meṣulamu, ọmọ Hodafaya, ọmọ Hasenua, Ibineaya, ọmọ Jerohamu, Ela, ọmọ Usi, ọmọ Mikiri, Meṣulamu, ọmọ Ṣefataya, ọmọ Reueli, ọmọ Ibinija. Àwọn ìbátan wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti tò wọ́n sinu ìwé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ó lé mẹrindinlọgọta (956). Gbogbo wọn jẹ́ baálé ninu ìdílé wọn, tí ń gbé Jerusalẹmu. Àwọn alufaa tí wọn ń gbé Jerusalẹmu nìwọ̀nyí: Jedaaya, Jehoiaribu, Jakini, ati Asaraya ọmọ Hilikaya, ọmọ Meṣulamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraiotu, ọmọ Ahitubu, olórí àwọn òṣìṣẹ́ ní ilé Ọlọrun; ati Adaaya, ọmọ Jerohamu, ọmọ Paṣuri, ọmọ Malikija ati Maasai ọmọ Adieli, ọmọ Jasera, ọmọ Meṣulamu, ọmọ Meṣilemiti, ọmọ Imeri. Àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ní ilé Ọlọrun láìka àwọn eniyan wọn ati àwọn olórí ìdílé wọn gbogbo jẹ́ ẹgbẹsan ó dín ogoji (1,760). Àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń gbé Jerusalẹmu nìwọ̀nyí: Ṣemaaya ọmọ Haṣihubu, ọmọ Asirikamu, ọmọ Haṣabaya, lára àwọn ọmọ Merari; ati Bakibakari, Hereṣi, Galali ati Matanaya ọmọ Mika, ọmọ Sikiri, ọmọ Asafu, ati Ọbadaya ọmọ Ṣemaaya, ọmọ Galali, ọmọ Jẹdutumu, ati Berekaya ọmọ Asa, ọmọ Elikana, tí ń gbé agbègbè tí àwọn ọmọ Netofa wà. Àwọn aṣọ́nà Tẹmpili nìwọ̀nyí: Ṣalumu, Akubu, Talimoni, Ahimani, ati àwọn eniyan wọn; (Ṣalumu ni olórí wọn). Wọ́n ń ṣọ́ apá ẹnu ọ̀nà ìlà oòrùn ilé ọba. Àwọn ni wọ́n ń ṣọ́ àgọ́ àwọn ọmọ Lefi tẹ́lẹ̀. Ṣalumu ọmọ Kore, ọmọ Ebiasafu, ọmọ Kora ati àwọn ará ilé baba rẹ̀. Gbogbo ìdílé Kora ni alabojuto iṣẹ́ ìsìn ninu tẹmpili ati olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọlé àgọ́, gẹ́gẹ́ bí baba wọn ti jẹ́ alabojuto Àgọ́ OLUWA ati olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọlé rẹ̀. Finehasi, ọmọ Eleasari ni olórí wọn tẹ́lẹ̀ rí, OLUWA sì wà pẹlu rẹ̀. Sakaraya, ọmọ Meṣelemaya ni olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. Gbogbo àwọn olùṣọ́nà tí wọ́n yàn láti máa ṣọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọlé jẹ́ igba ó lé mejila (212). A kọ orúkọ wọn sinu ìwé gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, ní agbègbè wọn. Dafidi ati Samuẹli aríran, ni wọ́n fi wọ́n sí ipò pataki náà. Nítorí náà, àwọn ati àwọn ọmọ wọn ni wọ́n ń ṣe alabojuto ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA, àwọn ni wọ́n fi ṣe olùṣọ́ Àgọ́ Àjọ. Ọ̀gá aṣọ́nà kọ̀ọ̀kan wà ní ẹnu ọ̀nà kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ mẹrẹẹrin: ní ìhà ìlà oòrùn, ati ìwọ̀ oòrùn, ati àríwá, ati gúsù; àwọn eniyan wọn tí wọn ń gbé àwọn ìletò a máa wá ní ọjọ́ meje meje, láti ìgbà dé ìgbà, láti wà pẹlu àwọn olórí ọ̀gá aṣọ́nà mẹrin náà. Nítorí àwọn olórí mẹrin wọnyi, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi, ni wọ́n tún ń ṣe alabojuto àwọn yàrá tẹmpili ati àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ninu ilé Ọlọrun. Wọ́n ń gbé àyíká ilé Ọlọrun, nítorí iṣẹ́ wọn ni láti máa bojútó o, ati láti máa ṣí ìlẹ̀kùn rẹ̀ ní àràárọ̀. Àwọn kan ninu àwọn ọmọ Lefi ni alabojuto àwọn ohun èlò ìjọ́sìn, iṣẹ́ wọn ni láti máa fún àwọn tí wọ́n ń lò wọ́n, ati láti gbà wọ́n pada sí ipò wọn, kí wọ́n sì kà wọ́n kí wọ́n rí i pé wọ́n pé. Iṣẹ́ àwọn mìíràn ninu wọn ni láti máa tọ́jú ohun ọ̀ṣọ́ tẹmpili ati ohun èlò mímọ́, ati ìyẹ̀fun ọkà, waini, òróró, turari, ati òjíá. Àwọn ọmọ alufaa yòókù ni wọ́n ń po turari, Matitaya, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Lefi tí ó jẹ́ àkọ́bí Ṣalumu ará Kora níí máa ń ṣe àkàrà ìrúbọ. Bákan náà, àwọn kan ninu àwọn ọmọ Kohati, ni wọ́n máa ń ṣe ìtọ́jú àkàrà ìfihàn ní ọjọọjọ́ ìsinmi. Àwọn ọmọ Lefi kan wà fún orin kíkọ ninu tẹmpili, wọ́n jẹ́ baálé baálé ninu ẹ̀yà Lefi, ninu àwọn yàrá tí ó wà ninu tẹmpili ni àwọn ń gbé, wọn kì í bá àwọn yòókù ṣiṣẹ́ mìíràn ninu tẹmpili, nítorí pé iṣẹ́ tiwọn ni orin kíkọ tọ̀sán-tòru. Baálé baálé ni àwọn tí a ti dárúkọ wọnyi ninu ìdílé wọn, olórí ni wọ́n ninu ẹ̀yà Lefi, wọ́n ń gbé Jerusalẹmu. Jeieli, baba Gibeoni ń gbé ìlú Gibeoni, iyawo rẹ̀ ń jẹ́ Maaka, Abidoni ni àkọ́bí rẹ̀, lẹ́yìn náà ni ó bí: Suri, Kiṣi, Baali, Neri, ati Nadabu; Gedori, Ahio, Sakaraya, ati Mikilotu; Mikilotu bí Ṣimea; àwọn náà ń gbé lọ́dọ̀ àwọn eniyan wọn ni òdìkejì ibùgbé àwọn arakunrin wọn ní Jerusalẹmu. Neri ni ó bí Kiṣi, Kiṣi bí Saulu, Saulu ni baba Jonatani, Malikiṣua, Abinadabu, ati Eṣibaali. Jonatani ni ó bí Meribibaali; Meribibaali sì bí Mika. Mika bí ọmọkunrin mẹrin: Pitoni, Meleki, Tarea ati Ahasi; Ahasi sì bí Jara. Jara bí ọmọ mẹta: Alemeti, Asimafeti ati Simiri, Simiri bí Mosa, Mosa sì bí Binea. Binea ni baba Refaaya, Refaaya ni ó bí Eleasa, Eleasa sì bí Aseli. Aseli bí ọmọkunrin mẹfa: Asirikamu, Bokeru, ati Iṣimaeli, Ṣearaya, Ọbadaya, ati Hanani. Ogun bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ará Filistia ati àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ọmọ Israẹli sá fún àwọn ará Filistia, wọ́n sì pa ọpọlọpọ àwọn ọmọ Israẹli ní orí òkè Giliboa. Ọwọ́ wọn tẹ Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n pa Jonatani, Abinadabu ati Malikiṣua. Ogun gbóná janjan yí Saulu ká, àwọn tafàtafà rí i, wọ́n ta á lọ́fà, ó sì fara gbọgbẹ́, Saulu ba sọ fún ọdọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀ pé, “Fa idà rẹ yọ, kí o sì gún mi pa, kí àwọn aláìkọlà ará Filistia má baà fi mi ṣẹ̀sín.” Ṣugbọn ẹni tí ń ru ihamọra rẹ̀ kọ̀, nítorí pe ẹ̀rù bà á; nítorí náà, Saulu fa idà ara rẹ̀ yọ, ó sì ṣubú lé e. Nígbà tí ọdọmọkunrin náà rí i pé Saulu kú, òun náà ṣubú lé idà rẹ̀, ó sì kú. Bẹ́ẹ̀ ni Saulu, àwọn ọmọ rẹ̀ mẹtẹẹta ati àwọn ará ilé rẹ̀ ṣe kú papọ̀. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli tí wọn ń gbé àfonífojì Jesireeli gbọ́ pé àwọn ọmọ ogun ti sá lọ, ati pé Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀ ti kú, wọ́n sá kúrò ní ìlú wọn, àwọn ará Filistia wá wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. Ní ọjọ́ keji, nígbà tí àwọn ará Filistia wá láti kó ìkógun, wọ́n rí òkú Saulu ati ti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹtẹẹta lórí Òkè Giliboa. Wọ́n bọ́ ihamọra Saulu, wọ́n gé orí rẹ̀, wọ́n sì rán àwọn oníṣẹ́ káàkiri gbogbo ilẹ̀ Filistini láti ròyìn ayọ̀ náà fún àwọn oriṣa wọn ati àwọn eniyan wọn. Wọ́n kó àwọn ihamọra rẹ̀ sinu tẹmpili oriṣa wọn, wọ́n sì kan orí Saulu mọ́ ara ògiri tẹmpili Dagoni, oriṣa wọn. Nígbà tí àwọn ará Jabeṣi Gileadi gbọ́ bí àwọn ará Filistia ti ṣe Saulu, gbogbo àwọn akọni ọkunrin tí wọ́n gbóyà gidigidi gbéra, wọ́n lọ gbé òkú Saulu ati òkú àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí Jabeṣi, wọ́n sì sin egungun wọn sí abẹ́ igi oaku ní Jabeṣi, wọ́n sì gbààwẹ̀ fún ọjọ́ meje. Bẹ́ẹ̀ ni Saulu ṣe kú nítorí aiṣododo rẹ̀; ó ṣàìgbọràn sí àṣẹ OLUWA, ó sì lọ ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ abókùúsọ̀rọ̀, ó lọ bèèrè ìtọ́sọ́nà níbẹ̀, dípò kí ó bèèrè ìtọ́sọ́nà lọ́wọ́ OLUWA. Nítorí náà, OLUWA pa á, ó sì gbé ìjọba rẹ̀ fún Dafidi, ọmọ Jese. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá parapọ̀, wọ́n wá sọ́dọ̀ Dafidi ní Heburoni, wọ́n ní, “Wò ó, ẹ̀jẹ̀ kan náà ni gbogbo wa pẹlu rẹ. Látẹ̀yìnwá, nígbà tí Saulu pàápàá wà lórí oyè, ìwọ ni ò ń ṣáájú Israẹli lójú ogun. OLUWA Ọlọrun rẹ sì ti ṣèlérí fún ọ pé ìwọ ni o óo máa ṣe olùṣọ́ àwọn ọmọ Israẹli, eniyan òun, tí o óo sì jọba lé wọn lórí.” Nítorí náà, àwọn àgbààgbà Israẹli wá sọ́dọ̀ Dafidi ọba, ní Heburoni. Dafidi sì bá wọn dá majẹmu níbẹ̀ níwájú OLUWA. Wọ́n fi òróró yàn án ní ọba lórí Israẹli, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA láti ẹnu Samuẹli. Dafidi ati àwọn ọmọ Israẹli lọ gbógun ti ìlú Jerusalẹmu, (Jebusi ni orúkọ Jerusalẹmu nígbà náà, ibẹ̀ ni àwọn ará Jebusi ń gbé.) Àwọn ará Jebusi sọ fún Dafidi pé, “O ò ní wọ ìlú yìí.” Ṣugbọn Dafidi ṣẹgun ibi ààbò Sioni, tí à ń pè ní ìlú Dafidi. Dafidi ní, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ pa ará Jebusi kan ni yóo jẹ́ balogun fún àwọn ọmọ ogun mi.” Joabu, ọmọ Seruaya ni ó kọ́kọ́ lọ, ó sì di balogun. Dafidi lọ ń gbé ibi ààbò náà, nítorí náà ni wọ́n ṣe ń pe ibẹ̀ ní ìlú Dafidi. Ó tún ìlú náà kọ́ yípo, bẹ̀rẹ̀ láti Milo, ibi tí a ti kun ilẹ̀ náà yíká. Joabu sì parí èyí tí ó kù. Dafidi bẹ̀rẹ̀ sí di alágbára sí i, nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun wà pẹlu rẹ̀. Àwọn tí wọ́n jẹ́ olórí ninu àwọn akọni ọmọ ogun Dafidi nìwọ̀nyí; àwọn ni wọ́n fọwọsowọpọ pẹlu àwọn ọmọ Israẹli, láti fi Dafidi jọba, tí wọ́n sì fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí OLUWA ti ṣe fún Israẹli. Àkọsílẹ̀ orúkọ wọn nìyí: Jaṣobeamu láti ìdílé Hakimoni ni olórí àwọn ọ̀gágun olókìkí mẹta. Òun ni ó fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ pa ọọdunrun (300) eniyan ninu ogun kan ṣoṣo. Ẹni tí ó tẹ̀lé e ninu àwọn ọ̀gágun olókìkí mẹta náà ni Eleasari ọmọ Dodo ará Aho. Ó wà pẹlu Dafidi nígbà tí Dafidi bá àwọn ará Filistia jagun ní Pasi Damimu, wọ́n wà ninu oko ọkà baali kan nígbà tí àwọn ọmọ ogun Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí sá fún àwọn ará Filistia. Ṣugbọn òun ati àwọn eniyan rẹ̀ dúró gbọningbọnin ninu oko náà, wọ́n bá àwọn ará Filistia jà. OLUWA gbà wọ́n, ó sì fún wọn ní ìṣẹ́gun ńlá. Ní ọjọ́ kan, mẹta ninu àwọn ọgbọ̀n ọ̀gágun olókìkí lọ sọ́dọ̀ Dafidi nígbà tí ó wà ní ihò Adulamu, nígbà tí àwọn ọmọ ogun Filistini dó sí àfonífojì Refaimu. Ibi ààbò ni Dafidi wà nígbà náà, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ogun Filistini sì ti wọ Bẹtilẹhẹmu, Dafidi ranti ilé, ó ní, “Kì bá ti dùn tó kí n rí ẹni fún mi ní omi mu láti inú kànga tí ó wà lẹ́nu ibodè Bẹtilẹhẹmu!” Àwọn akọni mẹta náà bá la àgọ́ àwọn ọmọ ogun Filistia já, dé ibi kànga náà, wọ́n sì bu omi náà wá fún Dafidi. Ṣugbọn ó kọ̀, kò mu ún; kàkà bẹ́ẹ̀, ó tú u sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fún OLUWA. Ó ní, “Kí á má rí i pé mo ṣe nǹkan yìí níwájú Ọlọrun mi. Ǹjẹ́ ó yẹ kí n mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ọkunrin wọnyi?” Nítorí pé ẹ̀mí wọn ni wọ́n fi wéwu kí wọn tó rí omi yìí bù wá; nítorí náà ni ó ṣe kọ̀, tí kò sì mu ún. Ó jẹ́ ohun ìgboyà tí àwọn akọni mẹta náà ṣe. Abiṣai, arakunrin Joabu, ni olórí àwọn ọgbọ̀n ọ̀gágun. Ó fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ pa ọọdunrun eniyan, nípa bẹ́ẹ̀ òkìkí tirẹ̀ náà súnmọ́ ti àwọn akọni mẹta náà. Òun ni ó lókìkí jùlọ ninu àwọn ọgbọ̀n ọ̀gágun náà, ó sì di olórí wọn; ṣugbọn kò ní òkìkí tó àwọn akọni mẹta. Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, láti ìlú Kabiseeli, jẹ́ ọmọ ogun tí ó ti ṣe ọpọlọpọ ohun ìyanu, ó pa àwọn abàmì eniyan meji ará Moabu. Ó wọ ihò lọ pa kinniun kan ní ọjọ́ kan tí yìnyín bo ilẹ̀. Ó pa ará Ijipti kan tí ó ga ju mita meji lọ. Ará Ijipti náà gbé ọ̀kọ̀ tí ó tóbi lọ́wọ́. Ṣugbọn kùmọ̀ ni Bẹnaya mú lọ́wọ́ lọ bá a, ó gba ọ̀kọ̀ tí ó wà lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì fi pa á. Àwọn ohun tí Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, ṣe nìyí, tí ó sọ ọ́ di olókìkí, yàtọ̀ sí ti àwọn akọni mẹta tí a sọ nípa wọn. Ó di olókìkí láàrin àwọn ọgbọ̀n ọ̀gágun; ṣugbọn òkìkí tirẹ̀ kò tó ti àwọn akọni mẹta náà. Dafidi bá fi ṣe olórí àwọn tí ń ṣọ́ ọba. Àwọn olókìkí mìíràn ninu àwọn ọmọ ogun Dafidi nìwọ̀nyí: Asaheli, arakunrin Joabu; ati Elihanani, ọmọ Dodo, ará Bẹtilẹhẹmu; Ṣamotu, láti Harodu; Helesi, láti inú ìdílé Peloni, Ira, ọmọ Ikeṣi ará Tekoa, ati Abieseri, láti Anatoti Sibekai, láti inú ìdílé Huṣati, ati Ilai, láti inú ìdílé Aho; Maharai, ará Netofa, ati Helodi, ọmọ Baana, ará Netofa; Itai, ọmọ Ribai, ará Gibea, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, ati Bẹnaya, ará Piratoni; Hurai, ará etí odò Gaaṣi, ati Abieli, ará Aribati; Asimafeti, ará Bahurumu, ati Eliaba ará Ṣaaliboni; Haṣemu, ará Gisoni, ati Jonatani, ọmọ Ṣagee, ará Harari; Ahiamu, ọmọ Sakari, ará Harari, ati Elifali, ọmọ Uri; Heferi, ará Mekerati, ati Ahija, ará Peloni; Hesiro, ará Kamẹli, ati Naarai ọmọ Esibai; Joẹli, arakunrin Natani, ati Mibihari, ọmọ Hagiri, Seleki, ará Amoni, ati Naharai, ará Beeroti, tí ń ru ihamọra Joabu ọmọ Seruaya. Ira, ará Itiri, ati Garebu ará Itiri, Uraya, ará Hiti, ati Sabadi, ọmọ Ahilai, Adina, ọmọ Ṣisa, láti inú ẹ̀yà Reubẹni, olórí kan láàrin ẹ̀yà Reubẹni, pẹlu ọgbọ̀n àwọn ọmọ ogun rẹ̀; Hanani, ọmọ Maaka, ati Joṣafati, ará Mitini; Usaya, ará Aṣiteratu, Ṣama, ati Jeieli, àwọn ọmọ Hotamu, ará Aroeri, Jediaeli, ọmọ Ṣimiri, ati Joha, arakunrin rẹ̀, ará Tisi, Elieli, ará Mahafi, ati Jẹribai, ati Joṣafia, àwọn ọmọ Elinaamu, ati Itima ará Moabu; Elieli, ati Obedi, ati Jaasieli, ará Mesoba. Àwọn ọkunrin wọnyi ni wọ́n lọ bá Dafidi ní Sikilagi, nígbà tí ó ń farapamọ́ fún Saulu, ọmọ Kiṣi; wọ́n wà lára àwọn akọni tí wọ́n ń ran Dafidi lọ́wọ́ lójú ogun. Tafàtafà ni wọ́n, wọ́n sì lè fi ọwọ́ ọ̀tún ati ọwọ́ òsì ta ọfà tabi kí wọ́n fi fi kànnàkànnà. Ninu ẹ̀yà Bẹnjamini ni wọ́n ti wá, wọ́n sì jẹ́ ìbátan Saulu. Olórí wọn ni Ahieseri, lẹ́yìn náà, Joaṣi, ọmọ Ṣemaa; ará Gibea ni àwọn mejeeji. Lẹ́yìn wọn ni: Jesieli ati Peleti, àwọn ọmọ Asimafeti; Beraka, ati Jehu, ará Anatoti. Iṣimaya, ará Gibeoni, akikanju jagunjagun ati ọ̀kan ninu “àwọn ọgbọ̀n” jagunjagun olókìkí ni, òun sì ni olórí wọn; Jeremaya, Jahasieli, Johanani ati Josabadi ará Gedera. Elusai, Jerimotu, ati Bealaya; Ṣemaraya, Ṣefataya ará Harifi; Elikana, Iṣaya, ati Asareli, Joeseri, ati Jaṣobeamu, láti inú ìdílé Kora, Joela, ati Sebadaya, àwọn ọmọ Jehoramu, ará Gedori. Àwọn ọkunrin tí wọ́n wá láti inú ẹ̀yà Gadi láti darapọ̀ mọ́ Dafidi, ní ibi ààbò tí ó wà ninu aṣálẹ̀ nìwọ̀nyí; akọni ati ògbólógbòó jagunjagun ni wọ́n, wọ́n já fáfá ninu lílo apata ati ọ̀kọ̀, ojú wọn dàbí ti kinniun, ẹsẹ̀ wọn sì yá nílẹ̀ bíi ti ẹsẹ̀ àgbọ̀nrín lórí òkè. Orúkọ wọn, ati bí wọ́n ṣe tẹ̀léra nìyí: Eseri ni olórí wọn, lẹ́yìn náà ni Ọbadaya, Eliabu; Miṣimana, Jeremaya, Atai, Elieli, Johanani, Elisabadi, Jeremaya, ati Makibanai. Àwọn ọmọ ẹ̀yà Gadi wọnyi ni olórí ogun, àwọn kan jẹ́ olórí ọgọrun-un ọmọ ogun, àwọn kan sì jẹ́ olórí ẹgbẹrun, olukuluku gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti jẹ́ akikanju sí. Àwọn ni wọ́n la odò Jọdani kọjá ninu oṣù kinni, ní àkókò ìgbà tí ó kún bo bèbè rẹ̀, wọ́n sì ṣẹgun gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní àfonífojì, ní apá ìhà ìlà oòrùn ati apá ìwọ̀ oòrùn. Àwọn kan láti inú ẹ̀yà Juda ati ti ẹ̀yà Bẹnjamini wá sọ́dọ̀ Dafidi níbi ààbò. Dafidi lọ pàdé wọn, ó ní, “Tí ẹ bá wá láti darapọ̀ mọ́ mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́, ati láti ràn mí lọ́wọ́, inú mi dùn sí yín; ṣugbọn bí ẹ bá wá ṣe amí fún àwọn ọ̀tá mi, nígbà tí ó ti jẹ́ pé n kò ní ẹ̀bi, Ọlọrun àwọn baba wa rí yín, yóo sì jẹ yín níyà.” Ẹ̀mí Ọlọrun bá bà lé Amasai, olórí àwọn ọgbọ̀n ọmọ ogun olókìkí, ó bá dáhùn pé, “Tìrẹ ni wá, Dafidi; a sì wà pẹlu rẹ, ọmọ Jese! Alaafia, alaafia ni fún ọ, alaafia sì ni fún àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ! Nítorí pé Ọlọrun rẹ ń ràn ọ́ lọ́wọ́.” Dafidi bá gbà wọ́n, ó sì fi wọ́n ṣe olórí àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Àwọn kan ninu ẹ̀yà Manase darapọ̀ mọ́ Dafidi nígbà tí òun pẹlu àwọn ará Filistia wá láti bá Saulu jagun. (Sibẹsibẹ kò lè ran àwọn Filistia lọ́wọ́, nítorí pé lẹ́yìn tí àwọn ọba àwọn Filistini jíròrò láàrin ara wọn, wọ́n ní “Ewu ń bẹ nítorí pé yóo darapọ̀ pẹlu Saulu, ọ̀gá rẹ̀.”) Wọ́n bá dá a pada lọ sí Sikilagi. Bí ó ti ń pada lọ sí Sikilagi, àwọn ará Manase kan wá, wọ́n bá darapọ̀ mọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Dafidi. Orúkọ wọn ni: Adina, Josabadi, Jediaeli, ati Mikaeli; Josabadi, Elihu ati Siletai, olórí ẹgbẹẹgbẹrun àwọn ọmọ ogun ninu ẹ̀yà Manase. Wọ́n ran Dafidi lọ́wọ́ láti gbógun ti àwọn ìgárá ọlọ́ṣà kan, nítorí pé gbogbo wọn ni wọ́n jẹ́ akọni jagunjagun, wọ́n sì jẹ́ ọ̀gágun. Lojoojumọ ni àwọn eniyan ń wá sọ́dọ̀ Dafidi láti ràn án lọ́wọ́; títí tí wọ́n fi pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n dàbí ogun ọ̀run. Àwọn ìpín ọmọ ogun Dafidi tí wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní Heburoni, láti gbé ìjọba Saulu lé Dafidi lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA nìyí: Láti inú ẹ̀yà Juda, àwọn ọmọ ogun tí wọ́n wá jẹ́ ẹẹdẹgbaarin ó dín igba (6,800) wọ́n di ihamọra pẹlu apata ati ọ̀kọ̀. Láti inú ẹ̀yà Simeoni, ẹẹdẹgbaarin ó lé ọgọrun-un (7,100), àwọn akọni jagunjagun ni wọ́n wá. Láti inú ẹ̀yà Lefi, wọ́n jẹ́ ẹẹdẹgbaata ó dín irinwo (4,600); Jehoiada, olóyè, wá láti inú ìran Aaroni pẹlu ẹgbaaji ó dín ọọdunrun (3,700) ọmọ ogun Sadoku ọdọmọkunrin akikanju jagunjagun wá, pẹlu ọ̀gágun mejilelogun ninu àwọn ará ilé baba rẹ̀. Láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà kan náà pẹlu Saulu, àwọn tí wọ́n wá jẹ́ ẹẹdẹgbaaji (3,000). Tẹ́lẹ̀ rí, ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini ni wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí ìdílé Saulu. Láti inú ẹ̀yà Efuraimu, ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹrin (20,800) akikanju ati alágbára, tí wọ́n jẹ́ olókìkí ninu ìdílé wọn ni wọ́n wá. Láti inú ìdajì ẹ̀yà Manase, ẹgbaasan-an (18,000) wá; yíyàn ni wọ́n yàn wọ́n láti lọ fi Dafidi jọba. Láti inú ẹ̀yà Isakari, àwọn igba (200) olórí ni wọ́n wá, àwọn tí wọ́n mọ ohun tí ó bá ìgbà mu, ati ohun tí ó yẹ kí Israẹli ṣe; wọ́n wá pẹlu àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ wọn. Láti inú ẹ̀yà Sebuluni, ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹgbaarun (50,000) àwọn ọmọ ogun, tí wọ́n gbóyà, tí wọ́n mọ̀ nípa ogun jíjà, tí wọ́n sì ní gbogbo ihamọra ogun ni wọ́n wá láti ran Dafidi lọ́wọ́ pẹlu ọkàn kan. Láti inú ẹ̀yà Nafutali, ẹgbẹrun (1,000) ọ̀gágun wá, ọ̀kẹ́ meji ó dín ẹẹdẹgbaaji (37,000) ni àwọn ọmọ ogun tí wọ́n wà pẹlu wọn; gbogbo wọn ní apata ati ọ̀kọ̀. Láti inú ẹ̀yà Dani, ẹgbaa mẹrinla ó lé ẹgbẹta ọkunrin (28,600) tí wọ́n dira ogun ni wọ́n wá. Láti inú ẹ̀yà Aṣeri, ọ̀kẹ́ meji (40,000) ni àwọn ọmọ ogun tí wọ́n ti dira ogun. Láti inú àwọn ẹ̀yà tí wọ́n wà ní ìhà ìlà oòrùn Jọdani, ẹ̀yà Reubẹni, ti Gadi, ati ìdajì ti Manase, ọ̀kẹ́ mẹfa (120,000) ọmọ ogun tí wọ́n ní gbogbo ihamọra ogun ni wọ́n wá. Gbogbo wọn ni wọ́n ti dira ogun, tí wọ́n wá sí Heburoni pẹlu ìpinnu láti fi Dafidi jọba lórí Israẹli. Àwọn ọmọ Israẹli yòókù náà sì pinnu bákan náà. Wọ́n wà níbẹ̀ pẹlu Dafidi fún ọjọ́ mẹta, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, nítorí àwọn arakunrin wọn ti pèsè oúnjẹ sílẹ̀ dè wọ́n. Bákan náà ni gbogbo àwọn aládùúgbò wọn láti ọ̀nà jíjìn bí ẹ̀yà Isakari ati ti Sebuluni ati Nafutali di oúnjẹ ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ati ràkúnmí, ati ìbakasíẹ, ati akọ mààlúù wá fún wọn. Wọ́n kó ọpọlọpọ oúnjẹ, àkàrà dídùn tí wọ́n fi èso ọ̀pọ̀tọ́ ṣe, ìdì èso resini, waini, ati òróró, pẹlu akọ mààlúù ati aguntan, nítorí pé ayọ̀ kún gbogbo orílẹ̀-èdè Israẹli. Dafidi jíròrò pẹlu àwọn ọ̀gágun ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun ati àwọn ti ọgọọgọrun-un, ati gbogbo àwọn olórí. Lẹ́yìn náà ó sọ fún gbogbo ìjọ Israẹli pé, “Bí ó bá dára lójú yín, tí ó sì jẹ́ ìfẹ́ OLUWA Ọlọrun wa, ẹ jẹ́ kí á ranṣẹ lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan wa tí wọ́n ṣẹ́kù ní ilé Israẹli, ati àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi ní àwọn ìlú tí wọ́n ní pápá oko, kí wọ́n wá darapọ̀ mọ́ wa. Kí á sì lọ sí ibi tí Àpótí Majẹmu Ọlọrun, tí a ti patì láti ayé Saulu wà, kí á gbé e pada wá sọ́dọ̀ wa.” Gbogbo ìjọ eniyan sì gbà bẹ́ẹ̀ nítorí pé ó dára lójú wọn. Nítorí náà Dafidi kó àwọn ọmọ Israẹli jọ láti Ṣihori ní Ijipti títí dé ẹnubodè Hamati láti lọ gbé Àpótí Majẹmu Ọlọrun láti Kiriati Jearimu lọ sí Jerusalẹmu. Dafidi ati gbogbo ọmọ Israẹli lọ sí ìlú Baala, tí à ń pè ní Kiriati Jearimu, ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Juda, wọ́n lọ gbé Àpótí Majẹmu tí à ń fi orúkọ OLUWA pè, OLUWA tí ó jókòó, tí ó fi àwọn Kerubu ṣe ìtẹ́. Wọ́n gbé Àpótí Majẹmu náà jáde láti ilé Abinadabu, wọ́n gbé e lé orí kẹ̀kẹ́ titun. Usa ati Ahio sì ń wa kẹ̀kẹ́ náà. Dafidi ati àwọn eniyan ń fi tagbára-tagbára jó níwájú Ọlọrun, pẹlu orin ati àwọn ohun èlò orin: dùùrù, hapu, ìlù, Kimbali ati fèrè. Bí wọ́n ti dé ibi ìpakà Kidoni, àwọn mààlúù tí wọn ń fa kẹ̀kẹ́ náà kọsẹ̀, Usa bá di Àpótí Majẹmu náà mú kí ó má baà ṣubú. Ṣugbọn inú bí Ọlọrun sí Usa, ó sì lù ú pa, nítorí pé ó fi ọwọ́ kan Àpótí Majẹmu, ó sì kú níwájú Ọlọrun. Inú bí Dafidi nítorí pé Ọlọrun lu Usa pa, láti ọjọ́ náà ni a ti ń pe ibẹ̀ ní Peresi Usa títí di òní. Ẹ̀rù Ọlọrun ba Dafidi ní ọjọ́ náà, ó ní, “Báwo ni mo ṣe lè gbé Àpótí Majẹmu Ọlọrun sọ́dọ̀?” Nítorí náà, Dafidi kò gbé Àpótí Majẹmu sọ́dọ̀ ara rẹ̀ ní ìlú Dafidi, kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbé e yà sí ilé Obedi Edomu, ará Giti. Àpótí Majẹmu Ọlọrun náà wà ní ilé Obedi Edomu yìí fún oṣù mẹta, OLUWA sì bukun ilé Obedi Edomu ati gbogbo ohun tí ó ní. Hiramu, ọba Tire kó àwọn òṣìṣẹ́ ranṣẹ sí Dafidi, pẹlu igi kedari ati àwọn ọ̀mọ̀lé ati àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà láti bá a kọ́ ilé rẹ̀. Dafidi ṣe akiyesi pé Ọlọrun ti fi ìdí ìjọba òun múlẹ̀ lórí Israẹli, ati pé Ọlọrun ti gbé ìjọba òun ga nítorí àwọn ọmọ Israẹli eniyan rẹ̀. Dafidi tún fẹ́ àwọn iyawo mìíràn ní Jerusalẹmu, ó sì bí àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin sí i. Àwọn tí ó bí ní Jerusalẹmu nìwọ̀nyí: Ṣamua, Ṣobabu, Natani, ati Solomoni; Ibihari, Eliṣua, ati Elipeleti; Noga, Nefegi, ati Jafia; Eliṣama, Beeliada, ati Elifeleti. Nígbà tí àwọn ará Filistia gbọ́ pé wọ́n ti fi òróró yan Dafidi lọ́ba lórí Israẹli, gbogbo wọn wá gbógun ti Dafidi. Nígbà tí Dafidi gbọ́, òun náà múra láti lọ gbógun tì wọ́n. Àwọn ará Filistia ti dé sí àfonífojì Refaimu, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbógun ti àwọn ìlú tí ó wà níbẹ̀, wọ́n sì ń kó wọn lẹ́rú. Dafidi bèèrè lọ́wọ́ Ọlọrun, ó ní: “Ṣé kí n lọ bá àwọn ará Filistia jà? Ṣé o óo jẹ́ kí n ṣẹgun wọn?” Ọlọrun dá a lóhùn pé, “Lọ bá wọn jà, n óo jẹ́ kí o ṣẹgun wọn.” Dafidi bá lọ kọlù wọ́n ní Baali Perasimu, ó sì ṣẹgun wọn, ó ní, “Ọlọrun ti lò mí láti kọlu àwọn ọ̀tá mi bí ìkún omi.” Nítorí náà ni a ṣe ń pe orúkọ ibẹ̀ ní Baali Perasimu. Àwọn ará Filistia fi oriṣa wọn sílẹ̀ nígbà tí wọn ń sá lọ, Dafidi sì pàṣẹ pé kí wọ́n sun wọ́n níná. Láìpẹ́, àwọn ará Filistia tún wá gbógun ti àwọn tí wọ́n wà ní àfonífojì, wọ́n sì kó wọn lẹ́rú. Dafidi bá tún lọ bèèrè lọ́wọ́ Ọlọrun. Ọlọrun sì dá a lóhùn pé, “Má ṣe bá wọn jà níhìn-ín, ṣugbọn yípo lọ sẹ́yìn wọn kí o kọlù wọ́n ní òdìkejì àwọn igi balisamu. Nígbà tí o bá ń gbọ́ ìró ẹsẹ̀ lórí àwọn igi balisamu ni kí o kọlù wọ́n, nítorí pé n óo ṣáájú rẹ lọ láti kọlu ogun Filistini.” Dafidi ṣe ohun tí Ọlọrun pa láṣẹ fún un, wọ́n pa àwọn ọmọ ogun Filistini láti Gibeoni títí dé Gasa. Òkìkí Dafidi kàn káàkiri, OLUWA sì jẹ́ kí ẹ̀rù rẹ̀ máa ba gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè. Dafidi kọ́ ọpọlọpọ ilé fún ara rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Ó tọ́jú ibìkan fún Àpótí Majẹmu Ọlọrun. Ó sì pa àgọ́ lé e lórí. Dafidi bá dáhùn pé, “Àwọn ọmọ Lefi nìkan ni wọ́n gbọdọ̀ ru Àpótí Majẹmu OLUWA, nítorí àwọn ni Ọlọrun yàn láti máa rù ú, ati láti máa ṣiṣẹ́ ìsìn rẹ̀ títí lae.” Nítorí náà, Dafidi pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sí Jerusalẹmu, kí wọ́n baà lè gbé Àpótí Majẹmu OLUWA wá sí ibi tí ó pèsè sílẹ̀ fún un. Dafidi kó àwọn ọmọ Aaroni ati àwọn ọmọ Lefi jọ: Iye àwọn ọmọ Lefi tí ó kó jọ láti inú ìdílé kọ̀ọ̀kan nìwọ̀nyí: láti inú ìdílé Kohati: ọgọfa (120) ọkunrin, Urieli ni olórí wọn; láti inú ìdílé Merari: igba ó lé ogún (220) ọkunrin, Asaaya ni olórí wọn, láti inú ìdílé Geriṣomu, aadoje (130) ọkunrin, Joẹli ni olórí wọn; láti inú ìdílé Elisafani, igba (200) ọkunrin, Ṣemaaya ni olórí wọn, láti inú ìdílé Heburoni, ọgọrin ọkunrin, Elieli ni olórí wọn, láti inú ìdílé Usieli, ọkunrin mejilelaadọfa (112), Aminadabu ni olórí wọn. Dafidi pe Sadoku ati Abiatari, àwọn alufaa, pẹlu àwọn olórí àwọn ọmọ Lefi mẹfa, Urieli, Asaaya, ati Joẹli, Ṣemaaya, Elieli, ati Aminadabu, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni olórí ìdílé yín ninu ẹ̀yà Lefi. Ẹ ya ara yín sí mímọ́, ẹ̀yin ati àwọn eniyan yín, kí ẹ baà lè gbé Àpótí Majẹmu OLUWA Ọlọrun Israẹli wá síbi tí mo ti tọ́jú sílẹ̀ fún un. Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ gbé e lákọ̀ọ́kọ́, OLUWA Ọlọrun wa jẹ wá níyà, nítorí pé a kò tọ́jú rẹ̀ bí ó ti tọ́.” Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi bá ya ara wọn sí mímọ́ láti gbé Àpótí Majẹmu OLUWA Ọlọrun Israẹli. Àwọn ọmọ Lefi fi ọ̀pá gbé e lé èjìká wọn gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pàṣẹ fún Mose. Dafidi pàṣẹ fún àwọn olórí ninu àwọn ọmọ Lefi pé kí wọ́n yan àwọn akọrin láàrin ara wọn, tí wọn yóo máa fi ohun èlò orin bíi hapu, dùùrù, ati aro dá orin ayọ̀. Nítorí náà àwọn ọmọ Lefi yan Hemani, ọmọ Joẹli ati Asafu, arakunrin rẹ̀, ọmọ Berekaya, ati àwọn arakunrin wọn láti ìdílé Merari, arakunrin wọn, Etani ọmọ Kuṣaaya. Wọ́n yan àwọn arakunrin wọn wọnyi kí wọ́n wà ní ipò keji sí wọn: Sakaraya, Jaasieli, Ṣemiramotu, Jehieli, Uni, Eliabu, Bẹnaya, Maaseaya, Matitaya, Elifelehu ati Mikineiya, pẹlu àwọn aṣọ́nà: Obedi Edomu ati Jeieli. Wọ́n yan àwọn akọrin, Hemani, Asafu ati Etani láti máa lu aro tí wọ́n fi idẹ ṣe Sakaraya, Asieli, Ṣemiramotu, Jehieli, Uni, Eliabu, Maaseaya ati Bẹnaya ń lo hapu, ṣugbọn Matitaya, Elifelehu, Mikineiya, Obedi Edomu, Jeieli ati Asasaya ni wọ́n ń tẹ dùùrù. Kenanaya ni a yàn láti máa darí orin àwọn ọmọ Lefi, nítorí pé ó ní ìmọ̀ orin. Berekaya ati Elikana ni wọ́n ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ibi tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu sí. Àwọn alufaa tí wọ́n yàn láti máa fọn fèrè níwájú Àpótí Majẹmu Ọlọrun ni: Ṣebanaya, Joṣafati, Netaneli, Amasa, Sakaraya, Bẹnaya, ati Elieseri. Obedi Edomu ati Jehaya pẹlu ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ibi tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu sí. Dafidi ati àwọn àgbààgbà Israẹli ati àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun bá lọ sí ilé Obedi Edomu, wọ́n lọ gbé Àpótí Majẹmu OLUWA pẹlu ayọ̀. Nítorí pé Ọlọrun ran àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ru Àpótí Majẹmu OLUWA lọ́wọ́, wọ́n fi mààlúù meje ati àgbò meje rúbọ. Dafidi ati gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ru Àpótí Majẹmu, ati àwọn akọrin ati Kenanaya, olórí àwọn akọrin wọ aṣọ funfun tí ń dán, Dafidi sì wọ efodu funfun. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Israẹli ṣe gbé Àpótí Majẹmu OLUWA pẹlu ìró orin ayọ̀, tí wọn ń fi oríṣìíríṣìí ohun èlò orin bíi ipè, fèrè, aro, hapu ati dùùrù kọ. Bí wọ́n ti ń gbé Àpótí Majẹmu OLUWA wọ ìlú Dafidi, Mikali ọmọbinrin Saulu yọjú láti ojú fèrèsé, ó rí Dafidi tí ń jó, tí ń fò sókè tayọ̀tayọ̀, ó sì pẹ̀gàn rẹ̀ ninu ara rẹ̀. Wọ́n gbé Àpótí Majẹmu Ọlọrun kalẹ̀ ninu àgọ́ tí Dafidi ti tọ́jú sílẹ̀ fún un, wọ́n sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia níwájú Ọlọrun. Nígbà tí Dafidi rú ẹbọ tán, ó súre fún àwọn eniyan ní orúkọ OLUWA, ó sì fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn, atọkunrin atobinrin, ní burẹdi kọ̀ọ̀kan, ati ègé ẹran yíyan kọ̀ọ̀kan ati àkàrà èso resini. Ó sì yan àwọn ọmọ Lefi kan láti máa ṣe ètò ìsìn níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA: láti máa gbadura, láti máa dúpẹ́, ati láti máa yin OLUWA Ọlọrun Israẹli. Asafu ni olórí, àwọn tí ipò wọn tún tẹ̀lé tirẹ̀ ni: Sakaraya, Jeieli, Ṣemiramotu, Jehieli, Matitaya, Eliabu, Bẹnaya, Obedi Edomu ati Jeieli àwọn tí wọ́n ń ta hapu, tí wọ́n sì ń tẹ dùùrù. Asafu ni ó ń lu aro. Bẹnaya ati Jahasieli, tí wọ́n jẹ́ alufaa, ni wọ́n ń fọn fèrè nígbà gbogbo níwájú Àpótí Majẹmu Ọlọrun. Ní ọjọ́ náà, àṣẹ àkọ́kọ́ tí Dafidi pa ni pé kí Asafu ati àwọn arakunrin rẹ̀ máa kọ orin ìyìn sí OLUWA. Ẹ fi ọpẹ́ fún OLUWA, ẹ képe orúkọ rẹ̀, ẹ kéde ohun tí ó ti ṣe fún àwọn orílẹ̀-èdè. Ẹ kọrin sí i, ẹ kọrin ìyìn sí i, ẹ sọ nípa àwọn ohun ìyanu tí ó ṣe! Ẹ máa fi orúkọ rẹ̀ ṣògo, kí ọkàn àwọn tí wọn ń sin OLUWA kún fún ayọ̀. OLUWA ni kí ẹ máa tọ̀ lọ fún ìrànlọ́wọ́, Ẹ máa sìn ín nígbà gbogbo. Ẹ ranti gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, gbogbo nǹkan ìyanu tí ó ṣe, ati gbogbo ìdájọ́ rẹ̀, ẹ̀yin ọmọ Abrahamu, iranṣẹ rẹ̀, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀. Òun ni OLUWA Ọlọrun wa, ìdájọ́ rẹ̀ ká gbogbo ayé. Kò ní í gbàgbé majẹmu rẹ̀ títí lae, àní àwọn ohun tí ó ti pa láṣẹ láti ṣe fún ẹgbẹẹgbẹrun ìran, majẹmu tí ó bá Abrahamu dá, ìlérí tí ó ti ṣe fún Isaaki, tí ó sì ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pẹlu Jakọbu, gẹ́gẹ́ bíi majẹmu ohun tí yóo wà títí lae, ó ní, “Ẹ̀yin ni n óo fún ní ilẹ̀ Kenaani, bí ohun ìní yín, tí ẹ óo jogún.” Nígbà tí wọn kò tíì pọ̀ pupọ, tí wọn kò sì jẹ́ nǹkan, tí wọ́n jẹ́ àjèjì níbẹ̀, tí wọn ń lọ káàkiri láti orílẹ̀-èdè kan dé ekeji, láti ìjọba kan sí òmíràn, kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ni wọ́n lára, ó bá àwọn ọba wí nítorí wọn. Ó ní, “Ẹ má ṣe fi ọwọ́ kan àwọn ẹni àmì òróró mi, ẹ má sì pa àwọn wolii mi lára!” Ẹ kọrin sí OLUWA, gbogbo ayé! Ẹ máa kéde ìgbàlà rẹ̀ lojoojumọ. Ẹ kéde ògo rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ polongo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrin àwọn eniyan! OLUWA tóbi, ìyìn tọ́ sí i lọpọlọpọ ó sì yẹ kí á bọ̀wọ̀ fún un ju gbogbo àwọn oriṣa lọ. Nítorí pé ère lásán ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù sọ di ọlọrun, ṣugbọn OLUWA ló dá ọ̀run. Ògo ati agbára yí i ká, ayọ̀ ati ìyìn sì kún Tẹmpili rẹ̀. Ẹ fi ògo fún OLUWA, gbogbo ayé, ẹ gbé ògo ati agbára wọ̀ ọ́! Ẹ fi ògo tí ó yẹ orúkọ OLUWA fún un, ẹ mú ọrẹ wá sí iwájú rẹ̀! Ẹ sin OLUWA pẹlu ẹwà mímọ́, ẹ wárìrì níwájú rẹ̀, gbogbo ayé, ó fi ìdí ayé múlẹ̀ gbọningbọnin kò sì lè yẹ̀ lae. Kí inú ọ̀run kí ó dùn, kí ayé kí ó yọ̀, kí wọ́n sọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè pé “OLUWA jọba!” Kí òkun ati ohun gbogbo tó wà ninu rẹ̀ hó yèè, kí pápá oko búsáyọ̀, ati gbogbo ẹ̀dá tó wà ninu rẹ̀. Àwọn igi igbó yóo kọrin ayọ̀ níwájú OLUWA, nítorí ó wá láti ṣe ìdájọ́ ayé. Ẹ fi ọpẹ́ fún OLUWA nítorí pé ó ṣeun, ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀ sì wà títí lae! Ẹ kígbe pé, “Gbà wá, Ọlọrun, olùgbàlà wa, kó wa jọ, sì gbà wá láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, kí á lè máa dúpẹ́, kí á máa yin orúkọ mímọ́ rẹ, kí á sì máa ṣògo ninu ìyìn rẹ. Ẹni ìyìn ni OLUWA, Ọlọrun Israẹli, lae ati laelae!” Gbogbo àwọn eniyan sì dáhùn pe, “Amin”, wọ́n sì yin OLUWA. Dafidi fi Asafu ati àwọn arakunrin rẹ̀ sí iwájú Àpótí Majẹmu OLUWA láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn níbẹ̀ lojoojumọ, pẹlu Obedi Edomu ati àwọn arakunrin rẹ̀ mejidinlaadọrin; ó sì fi Obedi Edomu, ọmọ Jedutuni ati Hosa ṣe aṣọ́nà. Ó fi Sadoku, alufaa ati àwọn alufaa ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sí ibi Àgọ́ OLUWA ní ibi pẹpẹ ìrúbọ tí ó wà ní Gibeoni, láti máa rú ẹbọ sísun sí OLUWA lórí pẹpẹ ẹbọ sísun, ní àràárọ̀ ati ní alaalẹ́, bí wọ́n ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ó ti pa á láṣẹ fún Israẹli. Hemani wà pẹlu wọn, ati Jedutuni ati àwọn mìíràn tí a yàn, tí a sì dárúkọ, láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA nítorí ìfẹ́ ńlá rẹ̀ tí kì í yẹ̀. Hemani ati Jedutuni ní fèrè, aro, ati àwọn ohun èlò ìkọrin mìíràn tí wọ́n fi ń kọrin ìyìn. Àwọn ọmọ Jedutuni ni wọ́n yàn láti máa ṣọ́ àwọn ẹnu ọ̀nà. Lẹ́yìn náà olukuluku pada sí ilé rẹ̀, Dafidi náà pada sí ilé rẹ̀ láti lọ súre fún àwọn ará ilé rẹ̀. Ní ọjọ́ kan ní àkókò tí Dafidi ọba ń gbe ààfin rẹ̀, ó sọ fún Natani, wolii, pé, “Wò ó, èmi ń gbé ilé tí a fi igi kedari kọ́, ṣugbọn Àpótí Majẹmu OLUWA wà ninu àgọ́.” Natani bá dá a lóhùn pé, “Ṣe gbogbo nǹkan tí ó wà lọ́kàn rẹ, nítorí pé Ọlọrun wà pẹlu rẹ.” Ṣugbọn ní alẹ́ ọjọ́ náà gan-an, Ọlọrun sọ fún Natani pé, “Lọ sọ fún Dafidi, iranṣẹ mi, pé, èmi ‘OLUWA sọ pé kì í ṣe òun ni óo kọ́ ilé tí n óo máa gbé fún mi. Nítorí pé n kò tíì gbé inú ilé kankan láti ìgbà tí mo ti kó àwọn ọmọ Israẹli kúrò lóko ẹrú títí di òní. Inú àgọ́ kan ni mo ti ń dé inú àgọ́ mìíràn, tí mo sì ń lọ láti ibìkan dé ibòmíràn. Sọ pé, mo ní ninu gbogbo ibi tí mo ti ń bá àwọn ọmọ Israẹli lọ káàkiri, ǹjẹ́ mo tíì yanu bèèrè lọ́wọ́ onídàájọ́ kankan, lára àwọn tí mo pàṣẹ fún láti máa darí àwọn eniyan mi, pé kí wọ́n kọ́ ilé kedari fún mi?’ “Nítorí náà, sọ fún un pé, èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ní ‘mo mú un wá láti inú pápá, níbi tí ó ti ń da ẹran, pé kí ó wá jọba lórí, àwọn eniyan mi, Israẹli. Mo sì ń wà pẹlu rẹ̀ ní gbogbo ibi tí ó ń lọ, mo sì ti pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ run níwájú rẹ̀, n óo sì gbé orúkọ rẹ̀ ga bí orúkọ àwọn eniyan ńlá ayé. N óo yan ibìkan fún Israẹli, àwọn eniyan mi, n óo fìdí wọn múlẹ̀, wọn óo máa gbé ilẹ̀ wọn, ẹnikẹ́ni kò ní yọ wọ́n lẹ́nu mọ́, àwọn ìkà kò tún ní ṣe wọ́n lófò mọ́ bíi ti àtijọ́, nígbà tí mo ti yan àwọn adájọ́ láti darí Israẹli, àwọn eniyan mi. N óo tẹ orí àwọn ọ̀tá wọn ba. Bákan náà, èmi OLUWA ṣe ìlérí pe n óo fi ìdí ìdílé rẹ̀ múlẹ̀. Nígbà tí ọjọ́ bá pé tí ó bá kú, tí a sin ín pẹlu àwọn baba rẹ̀, n óo gbé ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ dìde, àní ọ̀kan ninu àwọn ọmọkunrin rẹ̀, n óo sì fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀. Yóo kọ́ ilé kan fún mi, n óo jẹ́ kí atọmọdọmọ rẹ̀ wà lórí ìtẹ́ títí lae. N óo jẹ́ baba fún un, yóo sì jẹ́ ọmọ fún mi. N kò ní yẹ ìfẹ́ ńlá mi tí mo ní sí i, bí mo ti yẹ ti Saulu, tí ó ṣáájú rẹ̀. N óo fi ẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ ní ilé mi ati ninu ìjọba mi títí lae. N óo sì fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ títí lae.’ ” Gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ni Natani sọ fún Dafidi, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí i lójú ìran. Dafidi bá lọ jókòó níwájú OLUWA, ó gbadura báyìí pé, “Kí ni èmi ati ilé mi jẹ́, tí o fi gbé mi dé ipò tí mo dé yìí? Gbogbo èyí kò sì tó nǹkan lójú rẹ, Ọlọrun, o tún ṣèlérí nípa ìdílé èmi iranṣẹ rẹ fún ọjọ́ iwájú, o sì ti fi bí àwọn ìran tí ń bọ̀ yóo ti rí hàn mí, OLUWA Ọlọrun! Kí ni mo tún lè sọ nípa iyì tí o bù fún èmi, iranṣẹ rẹ? Nítorí pé o mọ èmi iranṣẹ rẹ. OLUWA, nítorí ti èmi iranṣẹ rẹ, ati gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn rẹ, ni o fi ṣe àwọn nǹkan ńlá wọnyi, tí o sì fi wọ́n hàn. Kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ, OLUWA, kò sì sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn rẹ, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a ti fi etí wa gbọ́. Ní gbogbo ayé, orílẹ̀-èdè wo ni ó tún dàbí Israẹli, àwọn eniyan rẹ, tí ìwọ Ọlọrun rà pada láti jẹ́ eniyan rẹ, tí o sì sọ orúkọ rẹ̀ di ńlá nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu tí o ṣe nígbà tí ó lé àwọn orílẹ̀-èdè kúrò níwájú àwọn eniyan rẹ, tí o rà pada láti ilẹ̀ Ijipti? O ti sọ àwọn eniyan rẹ, Israẹli, di tìrẹ títí lae, ìwọ OLUWA sì di Ọlọrun wọn. “Nisinsinyii, OLUWA, jọ̀wọ́ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tí o sọ nípa èmi iranṣẹ rẹ ṣẹ, ati ti ìran mi lẹ́yìn ọ̀la, kí o sì ṣe bí o ti wí. Orúkọ rẹ yóo fìdí múlẹ̀ sí i, àwọn eniyan rẹ yóo sì máa gbé ọ́ ga títí lae, wọn yóo máa wí pé ‘OLUWA àwọn ọmọ ogun, tí ó jẹ́ Ọlọrun Israẹli ni Israẹli mọ̀ ní Ọlọrun,’ ati pé ìdílé Dafidi, iranṣẹ rẹ, yóo fìdí múlẹ̀ sí i níwájú rẹ. Nítorí pé ìwọ Ọlọrun mi, ti fi han èmi iranṣẹ rẹ pé o óo fìdí ìdílé mi múlẹ̀, nítorí náà ni mo ṣe ní ìgboyà láti gbadura sí ọ. OLUWA, ìwọ ni Ọlọrun, o ti ṣe ìlérí ohun rere yìí fún èmi iranṣẹ rẹ. Nítorí náà, jẹ́ kí ó wù ọ́ láti bukun ìdílé èmi iranṣẹ rẹ, kí ìdílé mi lè wà níwájú rẹ títí lae, nítorí ẹnikẹ́ni tí o bá bukun, olúwarẹ̀ di ẹni ibukun títí lae.” Lẹ́yìn náà, Dafidi gbógun ti àwọn Filistini, ó ṣẹgun wọn, ó sì jagun gba ìlú Gati ati àwọn ìletò agbègbè rẹ̀ lọ́wọ́ wọn. Dafidi ṣẹgun àwọn ará Moabu, wọ́n di iranṣẹ rẹ̀, wọ́n sì ń san ìṣákọ́lẹ̀ fún un. Ó ṣẹgun Hadadeseri, ọba Siria ní Soba, ní agbègbè ilẹ̀ Hamati, bí Hadadeseri tí ń lọ fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ létí odò Yufurate. Dafidi gba ẹgbẹrun (1,000) kẹ̀kẹ́ ogun, ẹẹdẹgbaarin (7,000) ọmọ ogun ẹlẹ́ṣin, ati ọ̀kẹ́ kan (20,000) ọmọ ogun lọ́wọ́ rẹ̀. Ó rọ́ àwọn ẹṣin náà lẹ́sẹ̀, ṣugbọn ó dá àwọn kan sí fún ọgọrun-un (100) kẹ̀kẹ́ ogun. Nígbà tí àwọn ará Siria wá láti Damasku, láti ran Hadadeseri, ọba Soba lọ́wọ́, Dafidi gbógun tì wọ́n, ó sì pa ẹgbaa mọkanla (22,000) ninu àwọn ọmọ ogun wọn. Dafidi fi àwọn ọmọ ogun ṣọ́ Siria ti Damasku, àwọn ará Siria di iranṣẹ Dafidi, wọ́n sì ń san ìṣákọ́lẹ̀ fún un. OLUWA fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibi tí ó lọ. Dafidi gba àwọn apata wúrà tí wọ́n wà lọ́wọ́ àwọn iranṣẹ Hadadeseri, ó kó wọn lọ sí Jerusalẹmu. Ó kó ọpọlọpọ idẹ ní Tibihati ati Kuni, tí wọ́n wà lábẹ́ Hadadeseri. Idẹ yìí ni Solomoni fi ṣe agbada omi ńlá ati òpó ati àwọn ohun èlò idẹ fún ilé OLUWA. Nígbà tí Toi, ọba Hamati gbọ́ pé Dafidi ti ṣẹgun gbogbo àwọn ọmọ ogun Hadadeseri, ọba Soba, ó rán Hadoramu, ọmọ rẹ̀, pé kí ó lọ kí Dafidi ọba, kí ó sì bá a yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun tí ó ní lórí Hadadeseri, nítorí Hadadeseri ti bá Toi pàápàá jagun ní ọpọlọpọ ìgbà. Toi sì fi oríṣìíríṣìí ohun èlò wúrà, fadaka, ati idẹ ranṣẹ sí Dafidi. Dafidi yà wọ́n sí mímọ́ fún OLUWA, fún iṣẹ́ ìsìn pẹlu àwọn fadaka ati wúrà tí ó gbà lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ti ṣẹgun: àwọn bíi Edomu ati Moabu, Amoni, Filistini ati Amaleki. Abiṣai, ọmọ Seruaya, ṣẹgun àwọn ará Edomu ní àfonífojì Iyọ̀, ó pa ẹgbaa mẹsan-an (18,000) ninu wọn. Ó fi àwọn ọmọ ogun sí Edomu, gbogbo àwọn ará Edomu sì di iranṣẹ Dafidi. OLUWA fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibi tí ó lọ. Dafidi jọba lórí gbogbo Israẹli, ó ń dá ẹjọ́ òtítọ́, ó sì ń ṣe ẹ̀tọ́ fún gbogbo àwọn eniyan. Joabu, ọmọ Seruaya, ni Balogun rẹ̀, Jehoṣafati, ọmọ Ahiludi ni olùtọ́jú àwọn àkọsílẹ̀. Sadoku, ọmọ Ahitubu ati Ahimeleki ọmọ Abiatari ni alufaa. Ṣafiṣa ni akọ̀wé ilé ẹjọ́. Bẹnaya, ọmọ Jehoiada ní ń ṣe àkóso àwọn Kereti ati Peleti tí wọn ń ṣọ́ ọba, àwọn ọmọ Dafidi lọkunrin ni wọ́n sì wà ní àwọn ipò tí ó ga ninu ìjọba rẹ̀. Nígbà tí ó yá, Nahaṣi, ọba àwọn ará Amoni kú, Hanuni ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Dafidi ní, “N óo fi ìfẹ́ hàn sí Hanuni bí baba rẹ̀ ti fi ìfẹ́ hàn sí mi.” Dafidi bá rán oníṣẹ́ lọ kí i kú àṣẹ̀yìndè baba rẹ̀. Àwọn oníṣẹ́ Dafidi bá lọ sọ́dọ̀ Hanuni ní ilẹ̀ Amoni láti bá a kẹ́dùn. Ṣugbọn àwọn ìjòyè ilẹ̀ Amoni sọ fún ọba pé, “Ṣé o rò pé Dafidi ń bọ̀wọ̀ fún baba rẹ ni ó ṣe rán oníṣẹ́ láti wá bá ọ kẹ́dùn? Rárá o. Ó rán wọn láti wá ṣe amí ilẹ̀ yìí ni, kí ó baà lè ṣẹgun rẹ.” Nítorí náà, Hanuni mú àwọn oníṣẹ́ Dafidi, ó fá irùngbọ̀n wọn, ó gé ẹ̀wù wọn ní ìbàdí, ó sì lé wọn jáde. Ojú tì wọ́n pupọ wọn kò lè pada sílé. Nígbà tí Dafidi gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn, ó ranṣẹ sí wọn pé kí wọ́n dúró sí Jẹriko títí tí irùngbọ̀n wọn yóo fi hù, lẹ́yìn náà kí wọ́n máa pada bọ̀ wá sílé. Nígbà tí àwọn ará Amoni rí i pé Dafidi ti kórìíra àwọn, Hanuni ati àwọn eniyan rẹ̀ fi ẹgbẹrun (1,000) talẹnti fadaka ranṣẹ sí Mesopotamia, ati sí Aramu-maaka ati sí Soba, láti yá kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin. Wọ́n yá ẹgbaa mẹrindinlogun (32,000) kẹ̀kẹ́ ogun, ati ọba Maaka pẹlu àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n wá, wọ́n sì pàgọ́ ogun wọn sí ẹ̀bá Medeba. Àwọn ará Amoni náà wá kó àwọn ọmọ ogun wọn jọ láti gbogbo ìlú wọn. Nígbà tí Dafidi gbọ́, ó rán Joabu ati gbogbo àwọn akọni jagunjagun rẹ̀ jáde lọ bá wọn. Àwọn ogun Amoni tò lẹ́sẹẹsẹ siwaju ẹnubodè ìlú wọn, ṣugbọn àwọn ọba tí wọ́n bẹ̀ lọ́wẹ̀ wà lọ́tọ̀ ninu pápá. Nígbà tí Joabu rí i pé àwọn ọ̀tá ti gbógun ti òun níwájú ati lẹ́yìn, ó yan àwọn akọni ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli láti dojú kọ àwọn ará Siria. Ó fi àwọn ọmọ ogun yòókù sí abẹ́ Abiṣai, arakunrin rẹ̀, wọ́n sì dojú kọ àwọn ọmọ ogun Amoni. Joabu ní, “Bí àwọn ọmọ ogun Siria bá lágbára jù fún mi, wá ràn mí lọ́wọ́, bí ó bá sì jẹ́ pé àwọn ọmọ ogun Amoni ni wọ́n bá lágbára jù fún ọ, n óo wá ràn ọ́ lọ́wọ́. Ṣe ọkàn rẹ gírí, jẹ́ kí á jà gidigidi fún àwọn eniyan wa, ati fún àwọn ìlú Ọlọrun wa; kí OLUWA ṣe ohun tí ó bá dára lójú rẹ̀.” Joabu ati àwọn ogun Israẹli súnmọ́ àwọn ọmọ ogun Siria láti bá wọn jà, ṣugbọn àwọn ọmọ ogun Siria sá fún wọn. Nígbà tí àwọn ará Amoni rí i pé àwọn ará Siria sá, àwọn náà sá fun Abiṣai, wọn sì wọ ìlú wọn lọ. Joabu bá pada sí Jerusalẹmu. Nígbà tí àwọn ará Siria rí i pé àwọn ará Israẹli ṣẹgun àwọn, wọ́n ranṣẹ lọ pe àwọn ọmọ ogun Siria tí wọ́n wà ni ìkọjá odò Yufurate, wọ́n sì fi wọ́n sí abẹ́ Ṣobaki, balogun Hadadeseri. Nígbà tí Dafidi gbọ́, ó kó gbogbo ọmọ ogun Israẹli jọ, wọ́n rékọjá odò Jọdani, wọ́n lọ dojú kọ ogun Siria, àwọn ọmọ ogun Siria bá bẹ̀rẹ̀ sí bá Dafidi jagun. Àwọn ogun Siria sá níwájú Israẹli. Dafidi pa ẹẹdẹgbaarin (7,000) àwọn tí wọn ń wa kẹ̀kẹ́-ogun ati ọ̀kẹ́ meji (40,000) ọmọ ogun ẹlẹ́sẹ̀, ó sì pa Ṣobaki olórí ogun Siria. Nígbà tí àwọn iranṣẹ Hadadeseri rí i pé Israẹli ti ṣẹgun àwọn, wọ́n bẹ Dafidi, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sìn ín. Nítorí náà, àwọn ará Siria kò wá ran àwọn ará Amoni lọ́wọ́ mọ́. Nígbà tí àkókò òtútù kọjá, ní àkókò tí àwọn ọba máa ń lọ jagun, Joabu gbógun ti ilẹ̀ Amoni; wọ́n dó ti ìlú Raba. Ṣugbọn Dafidi dúró ní Jerusalẹmu. Joabu gbógun ti Raba, ó sì ṣẹgun rẹ̀. Dafidi ṣí adé wúrà orí ọba wọn, ó sì rí i pé adé náà wọ̀n tó ìwọ̀n talẹnti wúrà kan, òkúta olówó iyebíye kan sì wà lára rẹ̀; wọ́n bá fi dé Dafidi lórí. Dafidi sì tún kó ọpọlọpọ ìkógun mìíràn ninu ìlú náà. Ó kó àwọn eniyan tí wọ́n wà ninu ìlú náà, ó sì ń fi wọ́n ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́: Àwọn kan ń lo ayùn, àwọn kan ń lo ọkọ́, àwọn mìíràn sì ń lo àáké. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ṣe sí gbogbo àwọn ìlú Amoni. Òun ati àwọn eniyan rẹ̀ bá pada sí Jerusalẹmu. Lẹ́yìn náà, ogun bẹ́ sílẹ̀ ní Geseri, láàrin àwọn ará Filistia ati àwọn ọmọ Israẹli. Sibekai, ará Huṣati, pa ìran òmìrán kan, ará Filistia, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sipai, àwọn ará Israẹli bá ṣẹgun àwọn ará Filistia. Ogun mìíràn tún bẹ́ sílẹ̀ pẹlu àwọn ará Filistia, Elihanani, ọmọ Jairi, pa Lahimi, arakunrin Goliati, ará Gati, tí ọ̀kọ̀ rẹ̀ tóbi tó òpó òfì ìhunṣọ. Ogun mìíràn tún bẹ́ sílẹ̀ ní Gati. Ọkunrin gbọ̀ngbọ̀nràn kan wà níbẹ̀, ìka mẹfa ni ó ní ní ọwọ́ kọ̀ọ̀kan ati ní ẹsẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ òmìrán ni òun náà. Nígbà tí ó ń fi àwọn ọmọ Israẹli ṣe ẹlẹ́yà, Jonatani, ọmọ Ṣimea, arakunrin Dafidi bá pa á. Ìran òmìrán, ará Gati ni àwọn mẹtẹẹta; Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ ni ó sì pa wọ́n. Satani fẹ́ ta jamba fún àwọn ọmọ Israẹli, nítorí náà ó gbó Dafidi láyà láti kà wọ́n. Dafidi sọ fún Joabu ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀ pé, “Ẹ lọ ka àwọn ọmọ Israẹli láti Beeriṣeba títí dé Dani, kí ẹ wá fún mi lábọ̀, kí n lè mọ iye wọn.” Ṣugbọn Joabu dáhùn pé, “Kí Ọlọrun jẹ́ kí àwọn eniyan rẹ̀ pọ̀ síi ní ìlọ́po ìlọ́po lọ́nà ọgọrun-un, ju iye tí wọ́n jẹ́ nisinsinyii lọ! Kabiyesi, ṣebí abẹ́ ìwọ oluwa mi ni gbogbo wọn wà? Kí ló wá dé tí o fi fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀? Kí ló dé tí o fi fẹ́ mú àwọn ọmọ Israẹli jẹ̀bi?” Ṣugbọn ti ọba ni ó ṣẹ, Joabu bá lọ kà wọ́n jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Israẹli, ó sì pada wá sí Jerusalẹmu. Joabu fún ọba ní iye àwọn ọkunrin tí wọ́n tó lọ sójú ogun. Wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ marundinlọgọta (1,100,000) ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli, ati ọ̀kẹ́ mẹtalelogun ó lé ẹgbaarun (470,000) ninu àwọn ẹ̀yà Juda. Nítorí pé àṣẹ tí ọba pa yìí burú lójú Joabu, kò ka àwọn ẹ̀yà Lefi ati ti Bẹnjamini. Inú Ọlọrun kò dùn sí ọ̀rọ̀ náà, nítorí náà ó jẹ àwọn ọmọ Israẹli níyà. Dafidi bá sọ fún Ọlọrun pé, “Mo ti dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá, níti ohun tí mo ṣe yìí. Mo sì bẹ̀bẹ̀ pé kí o dárí ẹ̀ṣẹ̀ yìí ji èmi iranṣẹ rẹ, nítorí pé ìwà òmùgọ̀ ni mo hù.” Ọlọrun bá rán Gadi, aríran Dafidi pé, “Lọ sọ fún Dafidi pé, ‘OLUWA ní, nǹkan mẹta ni òun fi siwaju rẹ, kí o yan èyí tí o bá fẹ́ kí òun ṣe sí ọ ninu wọn.’ ” Gadi bá lọ sọ́dọ̀ Dafidi ó lọ sọ fún un pé, “OLUWA ní kí o yan èyí tí o bá fẹ́ ninu àwọn nǹkan mẹta wọnyi: yálà kí ìyàn mú fún ọdún mẹta, tabi kí àwọn ọ̀tá rẹ máa lé ọ kiri, kí wọ́n sì máa fi idà pa yín fún oṣù mẹta, tabi kí idà OLUWA kọlù ọ́ fún ọjọ́ mẹta, kí àjàkálẹ̀ àrùn sọ̀kalẹ̀ sórí ilẹ̀ náà, kí angẹli Ọlọrun sì máa paniyan jákèjádò ilẹ̀ Israẹli. Sọ èyí tí o bá fẹ́, kí n lè mọ ohun tí n óo sọ fún ẹni tí ó rán mi.” Nígbà náà ni Dafidi wí fún Gadi pé, “Ìdààmú ńlá dé bá mi, jẹ́ kí n ṣubú sí ọwọ́ Ọlọrun, nítorí àánú rẹ̀ pọ̀; má jẹ́ kí n bọ́ sí ọwọ́ eniyan.” Nítorí náà, Ọlọrun rán àjàkálẹ̀ àrùn sórí ilẹ̀ Israẹli, àwọn tí wọ́n kú sì jẹ́ ẹgbaa marundinlogoji (70,000) eniyan. Ọlọrun rán angẹli kan pé kí ó lọ pa Jerusalẹmu run; ṣugbọn bí ó ti fẹ́ pa á run, OLUWA rí i, ó sì yí ọkàn pada, ó wí fún apanirun náà pé, “Ó tó gẹ́ẹ́, dáwọ́ dúró.” Angẹli OLUWA náà bá dúró níbi ìpakà Onani ará Jebusi. Dafidi rí angẹli náà tí ó dúró ní agbede meji ayé ati ọ̀run, tí ó na idà ọwọ́ rẹ̀ sí orí Jerusalẹmu. Dafidi ati àwọn ìjòyè àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀ bá dojúbolẹ̀. Dafidi bá sọ fún Ọlọrun pé, “Ṣebí èmi ni mo pàṣẹ pé kí wọ́n lọ ka àwọn eniyan? Èmi ni mo ṣẹ̀, tí mo sì ṣe nǹkan burúkú. Kí ni àwọn aguntan wọnyi ṣe? OLUWA, Ọlọrun mi, mo bẹ̀ ọ́, èmi ati ilé baba mi ni kí o jẹ níyà, má jẹ́ kí àjàkálẹ̀ àrùn yìí wá sórí àwọn eniyan rẹ.” Angẹli OLUWA bá pàṣẹ fún Gadi pé kí ó lọ sọ fún Dafidi pé kí ó lọ tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA ní ibi ìpakà Onani ará Jebusi. Dafidi bá dìde gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Gadi, tí ó sọ ní orúkọ OLÚWA. Onani ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin mẹrin wà níbi tí wọ́n ti ń pakà. Nígbà tí wọ́n rí angẹli náà, wọ́n sápamọ́. Bí Dafidi ti dé ọ̀dọ̀ Onani, tí Onani rí i, ó kúrò níbi tí ó ti ń pa ọkà, ó lọ tẹríba fún Dafidi, ó dojúbolẹ̀. Dafidi sọ fún un pé, “Ta ibi ìpakà yìí fún mi, kí n lè tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún OLUWA. Iye tí ó bá tó gan-an ni kí o tà á fún mi, kí àjàkálẹ̀ àrùn yìí lè dáwọ́ dúró.” Onani dá Dafidi lóhùn pé, “olúwa mi, mú gbogbo rẹ̀, kí o sì ṣe ohun tí o bá fẹ́ níbẹ̀. Wò ó, mo tún fún ọ ní àwọn akọ mààlúù yìí fún ẹbọ sísun, ati pákó ìpakà fún dídá iná ẹbọ sísun, ati ọkà fún ẹbọ ohun jíjẹ. Mo bùn ọ́ ní gbogbo rẹ̀.” Ṣugbọn Dafidi ọba dá Onani lóhùn pé, “Rárá o, mo níláti ra gbogbo rẹ̀ ní iye tí ó bá tó gan-an ni. N kò ní fún OLUWA ní nǹkan tí ó jẹ́ tìrẹ, tabi kí n rú ẹbọ tí kò ná mi ní ohunkohun sí OLUWA.” Nítorí náà, Dafidi fún Onani ní ẹgbẹta (600) ìwọ̀n ṣekeli wúrà, fún ilẹ̀ ìpakà náà. Dafidi tẹ́ pẹpẹ níbẹ̀, ó rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia, ó bá képe OLUWA. OLUWA dá a lóhùn: ó rán iná sọ̀kalẹ̀ láti jó ẹbọ sísun náà. OLUWA pàṣẹ fún angẹli náà pé kí ó ti idà rẹ̀ bọ inú àkọ̀, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tí Dafidi rí i pé OLUWA ti gbọ́ adura rẹ̀ ní ibi ìpakà Onani ará Jebusi, ó bẹ̀rẹ̀ sí rú àwọn ẹbọ rẹ̀ níbẹ̀. Títí di àkókò yìí, àgọ́ OLUWA tí Mose pa ní aṣálẹ̀, ati pẹpẹ ẹbọ sísun wà ní ibi pẹpẹ ìrúbọ ní Gibeoni. Ṣugbọn Dafidi kò lè lọ sibẹ láti wádìí lọ́wọ́ Ọlọrun nítorí ó ń bẹ̀rù idà angẹli OLUWA. Nítorí náà Dafidi pàṣẹ pé, “Ibí yìí ni ilé OLUWA Ọlọrun, ati pẹpẹ ẹbọ sísun yóo wà fún Israẹli.” Dafidi pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn àjèjì tí wọn ń gbé ilẹ̀ Israẹli péjọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí kó wọn ṣiṣẹ́, ara wọn ni wọ́n gbẹ́ òkúta fún kíkọ́ tẹmpili. Ó kó ọpọlọpọ irin jọ, tí wọn óo fi rọ ìṣó, tí wọn yóo fi kan àwọn ìlẹ̀kùn ati ìdè, ó kó idẹ jọ lọpọlọpọ pẹlu, ju ohun tí ẹnikẹ́ni lè wọ̀n lọ, ati ọpọlọpọ igi kedari. Ó pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí eniyan kò le kà wọ́n, nítorí pé ọpọlọpọ igi kedari ni àwọn ará Sidoni ati Tire kó wá fún Dafidi. Nítorí pe Dafidi ní, “Tẹmpili tí a óo kọ́ fún OLUWA gbọdọ̀ dára tóbẹ́ẹ̀ tí òkìkí rẹ̀ yóo kàn ká gbogbo ayé; bẹ́ẹ̀ sì ni Solomoni, ọmọ mi, tí yóo kọ́ ilé náà kéré, kò sì tíì ní ìrírí pupọ. Nítorí náà, n óo tọ́jú àwọn ohun èlò sílẹ̀ fún un.” Dafidi bá tọ́jú àwọn nǹkan tí wọn yóo lò sílẹ̀ lọpọlọpọ kí ó tó kú. Dafidi bá pe Solomoni, ọmọ rẹ̀, ó pàṣẹ fún un pé kí ó kọ́ ilé kan fún OLUWA Ọlọrun Israẹli. Ó ní, “Ọmọ mi, mo ní i lọ́kàn láti kọ́ tẹmpili kan fún orúkọ OLUWA Ọlọrun mi, ṣugbọn OLUWA sọ fún mi pé mo ti ta ọpọlọpọ ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, mo sì ti ja ọpọlọpọ ogun; nítorí ọpọlọpọ ìtàjẹ̀sílẹ̀ náà, òun kò ní gbà pé kí n kọ́ tẹmpili òun. OLUWA ní n óo bí ọmọkunrin kan tí ìjọba rẹ̀ yóo jẹ́ ìjọba alaafia, ó ní òun óo fún un ní alaafia, gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ yíká kò sì ní yọ ọ́ lẹ́nu. Solomoni ni orúkọ rẹ̀ yóo máa jẹ́. Ní ìgbà tirẹ̀, Israẹli yóo wà ní alaafia ati àìléwu. Ó ní ọmọ náà ni yóo kọ́ ilé fún òun. Yóo jẹ́ ọmọ òun, òun náà yóo sì jẹ́ baba rẹ̀. Ó ní òun óo fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ ní Israẹli títí lae. “Nisinsinyii, ìwọ ọmọ mi, OLUWA yóo wà pẹlu rẹ, kí o lè kọ́ ilé OLUWA Ọlọrun rẹ fún un gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ nípa rẹ. Kí OLUWA fún ọ ní ọgbọ́n ati làákàyè kí o lè máa pa òfin OLUWA Ọlọrun rẹ mọ́ nígbà tí ó bá fi ọ́ jọba lórí Israẹli. Bí o bá pa gbogbo òfin tí Ọlọrun fún Israẹli láti ọwọ́ Mose mọ́, o óo ṣe rere. Múra, kí o sì ṣe ọkàn gírí, má bẹ̀rù, má sì ṣe jẹ́ kí àyà fò ọ́. Mo ti sa gbogbo agbára mi láti tọ́jú ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) talẹnti wúrà kalẹ̀ fún kíkọ́ ilé OLUWA, aadọta ọ̀kẹ́ (1,000,000) talẹnti fadaka, ati idẹ, ati irin tí ó pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè wọ̀n. Mo ti tọ́jú òkúta ati pákó pẹlu. O gbọdọ̀ wá kún un. O ní ọpọlọpọ òṣìṣẹ́: àwọn agbẹ́kùúta, àwọn ọ̀mọ̀lé, àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, ati oríṣìíríṣìí àwọn oníṣẹ́ ọnà tí kò lóǹkà, àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà, ati ti fadaka, ti idẹ, ati ti irin. Bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà nisinsinyii! Kí OLUWA wà pẹlu rẹ!” Dafidi pàṣẹ fún gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli pé kí wọ́n ran Solomoni, ọmọ òun lọ́wọ́. Ó ní, “Ǹjẹ́ OLUWA Ọlọrun yín kò ha wà pẹlu yín? Ǹjẹ́ kò ti fun yín ní ìfọ̀kànbalẹ̀ káàkiri? Nítorí pé ó ti jẹ́ kí n ṣẹgun gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yìí, ilẹ̀ náà sì wà lábẹ́ àkóso OLUWA ati ti àwọn eniyan rẹ̀. Nítorí náà, ẹ fi tọkàntọkàn wá OLUWA Ọlọrun yín nisinsinyii. Ẹ múra kí ẹ kọ́ ilé ìsìn fún OLUWA Ọlọrun, kí ẹ baà lè gbé Àpótí Majẹmu OLUWA ati gbogbo ohun èlò mímọ́ fún ìsìn Ọlọrun lọ sinu ilé tí ẹ óo kọ́ fún OLUWA.” Nígbà tí Dafidi dàgbà, tí ó di arúgbó, ó fi Solomoni, ọmọ rẹ̀ jọba lórí Israẹli. Dafidi pe gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli, àwọn alufaa ati àwọn Lefi jọ. Ó ka gbogbo àwọn Lefi tí wọ́n jẹ́ ọkunrin tí wọ́n dàgbà tó ọmọ ọgbọ̀n ọdún sókè, gbogbo wọn jẹ́ ẹgbaa mọkandinlogun (38,000). Dafidi fún ẹgbaa mejila (24,000) ninu wọn ní iṣẹ́ ninu tẹmpili; ó ní kí ẹgbaata (6,000) máa ṣe àkọsílẹ̀ ati ìdájọ́ àwọn eniyan, kí ẹgbaaji (4,000) máa ṣọ́nà, kí ẹgbaaji (4,000) sì máa yin OLUWA pẹlu oríṣìíríṣìí ohun èlò orin tí ọba pèsè. Dafidi pín àwọn ọmọ Lefi ní ìdílé ìdílé: ti Geriṣomu, ti Kohati, ati ti Merari. Àwọn ọmọ Geriṣomu jẹ́ meji: Ladani ati Ṣimei; Àwọn ọmọ Ladani jẹ́ mẹta: Jeieli tí ó jẹ́ olórí, Setamu ati Joẹli. Àwọn ọmọ Ṣimei ni Ṣelomoti, Hasieli, ati Harani; àwọn ni wọ́n jẹ́ olórí ìdílé Ladani. Àwọn ọmọ Ṣimei jẹ́ mẹrin: Jahati, Sina, Jeuṣi, ati Beraya. Jahati ni ó jẹ́ olórí, Sisa ni igbákejì rẹ̀, ṣugbọn Jeuṣi ati Beraya kò bí ọmọ pupọ, nítorí náà ni wọ́n fi kà wọ́n sí ìdílé kan ninu ọ̀kan ninu àwọn àkọsílẹ̀. Àwọn ọmọ Kohati jẹ́ mẹrin: Amramu, Iṣari, Heburoni, ati Usieli, Àwọn ọmọ Amramu ni Aaroni ati Mose. Aaroni ni a yà sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ibi mímọ́, pé kí òun ati àwọn ìran rẹ̀ títí lae máa sun turari níwájú OLUWA, kí wọ́n máa darí ìsìn OLUWA, kí wọ́n sì máa súre fún àwọn eniyan ní orúkọ rẹ̀ títí lae. A ka àwọn ọmọ Mose, iranṣẹ Ọlọrun, pọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀yà Lefi. Mose bí ọmọkunrin meji: Geriṣomu ati Elieseri. Àwọn ọmọ Geriṣomu ni: Ṣebueli, olórí ìdílé Geriṣomu. Elieseri bí ọmọkunrin kan tí ń jẹ́ Rehabaya, olórí ìdílé rẹ̀, kò sì bí ọmọ mìíràn mọ́, ṣugbọn àwọn ọmọ Rehabaya pọ̀. Iṣari bí ọmọkunrin kan, Ṣelomiti, tí ó jẹ́ olórí ìdílé rẹ̀. Heburoni bí ọmọ mẹrin: Jeraya, tí ó jẹ́ olórí, lẹ́yìn rẹ̀ ni Amaraya, Jahasieli, Jekameamu. Usieli bí ọmọ meji: Mika, tí ó jẹ́ olórí, ati Iṣaya. Merari bí ọmọkunrin meji: Mahili ati Muṣi. Mahili bí ọmọkunrin meji: Eleasari ati Kiṣi, Ṣugbọn Eleasari kú láì ní ọmọkunrin kankan; kìkì ọmọbinrin ni ó bí. Àwọn ọmọbinrin rẹ̀ bá fẹ́ àwọn ọmọ Kiṣi, àbúrò baba wọn. Àwọn ọmọ Muṣi jẹ́ mẹta: Mahili, Ederi ati Jeremotu. Àwọn ni baálé baálé ninu ìran Lefi, ní ìdílé ìdílé, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ àwọn tí wọ́n tó ogún ọdún ati jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí wọ́n dàgbà tó láti ṣiṣẹ́ ninu ilé OLUWA. Dafidi ní, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ti fún àwọn eniyan rẹ̀ ní ìsinmi, yóo sì máa gbé Jerusalẹmu títí lae. Nítorí náà, àwọn ẹ̀yà Lefi kò ní máa ru Àgọ́ Àjọ ati àwọn ohun èlò tí wọn ń lò ninu rẹ̀ káàkiri mọ́.” Gẹ́gẹ́ bí ètò tí Dafidi ti ṣe, iye àwọn ọmọ Lefi láti ogún ọdún sókè nìyí: Ṣugbọn iṣẹ́ wọn ni láti máa ran àwọn ọmọ Aaroni lọ́wọ́ ninu iṣẹ́ ìsìn ilé OLUWA, láti máa ṣe ìtọ́jú àgbàlá ati àwọn yàrá ibẹ̀, láti rí i pé àwọn ohun èlò ilé OLUWA wà ní mímọ́, ati láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ mìíràn tí ó yẹ ninu ilé OLUWA. Àwọn ni wọ́n tún ń ṣe ètò ṣíṣe burẹdi ìfihàn, ìyẹ̀fun fún ẹbọ ohun jíjẹ, àkàrà tí kò ní ìwúkàrà ninu, àkàrà díndín fún ẹbọ, ẹbọ tí a po òróró mọ́, ati pípèsè àwọn oríṣìíríṣìí ìwọ̀n. Wọn yóo máa kọrin ìyìn sí OLUWA ní àràárọ̀, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ní ìrọ̀lẹ́ ìrọ̀lẹ́, ati nígbàkúùgbà tí wọ́n bá ń rúbọ sí OLUWA ní ọjọ́ ìsinmi, ọjọ́ oṣù titun, tabi ọjọ́ àjọ̀dún, gẹ́gẹ́ bí iye àwọn tí a yàn láti máa kọrin níwájú OLUWA nígbà gbogbo. Bẹ́ẹ̀ ni wọn yóo ṣe máa bojútó Àgọ́ Àjọ ati ibi mímọ́, tí wọn yóo sì máa ran àwọn ọmọ Aaroni, àwọn arakunrin wọn lọ́wọ́, níbi iṣẹ́ ìsìn ilé OLUWA. Bí a ṣe pín àwọn ọmọ Aaroni nìyí: Aaroni ní ọmọkunrin mẹrin: Nadabu, Abihu, Eleasari ati Itamari. Nadabu ati Abihu kú ṣáájú baba wọn láì bí ọmọ kankan. Nítorí náà, Eleasari, ati Itamari di alufaa. Pẹlu ìrànlọ́wọ́ Sadoku ọmọ Eleasari ati Ahimeleki ọmọ Itamari, Dafidi pín àwọn ọmọ Aaroni sí ẹgbẹẹgbẹ́ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tí wọn ń ṣe ninu iṣẹ́ ìsìn. Àwọn tí wọ́n jẹ́ baálé baálé pọ̀ ninu àwọn ọmọ Eleasari ju ti Itamari lọ, nítorí náà, wọ́n pín àwọn ọmọ Eleasari sí abẹ́ àwọn baálé baálé mẹrindinlogun, wọ́n sì pín àwọn ọmọ Itamari sí abẹ́ àwọn baálé baálé mẹjọ. Bí wọ́n ṣe pín wọn kò sì fì sí ibìkan nítorí pé gègé ni wọ́n ṣẹ́ tí wọ́n fi yàn wọ́n, nítorí pé, bí àwọn alámòójútó ìsìn ati alámòójútó iṣẹ́ ilé Ọlọrun ṣe wà ninu àwọn ìran Eleasari, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n wà ninu ti Itamari. Ṣemaaya, akọ̀wé, ọmọ Netaneli, láti inú ẹ̀yà Lefi, ni ó kọ orúkọ wọn sílẹ̀ níwájú ọba ati àwọn ìjòyè, ati Sadoku, alufaa, ati Ahimeleki, ọmọ Abiatari, ati àwọn baálé baálé ninu ìdílé àwọn alufaa, ati ti àwọn ọmọ Lefi. Bí wọ́n bá ti mú ọ̀kan láti inú ìran Eleasari, wọn á sì tún mú ọ̀kan láti ìran Itamari. Gègé tí wọ́n kọ́kọ́ ṣẹ́ mú Jehoiaribu, ekeji mú Jedaaya. Gègé sì mú àwọn yòókù wọnyi tẹ̀léra wọn báyìí: Harimu, Seorimu; Malikija, Mijamini; Hakosi, Abija, Jeṣua, Ṣekanaya; Eliaṣibu, Jakimu, Hupa, Jeṣebeabu; Biliga, Imeri, Hesiri, Hapisesi; Petahaya, Jehesikeli, Jakini, Gamuli; Delaaya, Maasaya. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n óo ṣe tẹ̀léra wọn níbi iṣẹ́ ṣíṣe ninu ilé OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Aaroni, baba wọn, ti là sílẹ̀ fún wọn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA Ọlọrun pa fún Israẹli. Àwọn olórí ninu ìdílé àwọn ọmọ Lefi yòókù nìwọ̀nyí: Ṣubaeli láti inú ìdílé Amramu, Jedeaya láti inú ìdílé Ṣubaeli. Iṣaya tí ó jẹ́ olórí láti inú ìdílé Rehabaya, Ṣelomiti láti inú ìdílé Iṣari, Jahati láti inú ìdílé Ṣelomiti. Àwọn ọmọ Heburoni jẹ́ mẹrin: Jeraya ni olórí wọn, bí àwọn yòókù wọn ṣe tẹ̀léra nìyí: Amaraya, Jahasieli ati Jekameamu. Mika láti inú ìdílé Usieli, Ṣamiri láti inú ìdílé Mika. Iṣaya ni arakunrin Mika. Sakaraya láti inú ìdílé Iṣaya. Mahili ati Muṣi láti inú ìdílé Merari. Àwọn ọmọ Merari láti inú ìdílé Jaasaya ni Beno ati Ṣohamu, Sakuri ati Ibiri. Eleasari láti inú ìdílé Mahili, Eleasari kò bí ọmọkunrin kankan. Jerameeli ọmọ Kiṣi, láti ìdílé Kiṣi. Muṣi ní ọmọkunrin mẹta: Mahili, Ederi, ati Jerimotu. Àkọsílẹ̀ àwọn ọmọ Lefi nìyí, gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn. Àwọn olórí ìdílé náà ṣẹ́ gègé gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Aaroni, àwọn arakunrin wọn ti ṣe, níwájú ọba Dafidi, ati Sadoku, ati Ahimeleki, pẹlu àwọn olórí ninu ìdílé alufaa ati ti àwọn ọmọ Lefi. Dafidi ati àwọn olórí ogun ya àwọn kan sọ́tọ̀ ninu àwọn ọmọ Asafu, Hemani ati ti Jedutuni láti máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń fi dùùrù, ati hapu ati aro kọrin. Àkọsílẹ̀ àwọn tí a yàn ati iṣẹ́ wọn nìyí: Lára àwọn ọmọ Asafu wọ́n yan Sakuri, Josẹfu, Netanaya, ati Asarela; wọ́n wà lábẹ́ àkóso Asafu, wọn a sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ lábẹ́ àkóso ọba. Àwọn ọmọ Jedutuni jẹ́ mẹfa: Gedalaya, Seri, ati Jeṣaaya; Ṣimei, Haṣabaya ati Matitaya, abẹ́ àkóso Jedutuni, baba wọn, ni wọ́n wà, wọn a sì máa fi dùùrù sọ àsọtẹ́lẹ̀ ninu orin ọpẹ́ ati ìyìn sí OLUWA. Àwọn ọmọ Hemani ni: Bukaya, Matanaya, Usieli, Ṣebueli, ati Jerimotu, Hananaya, Hanani, Eliata, Gidaliti, ati Romamiti Eseri, Joṣibekaṣa, Maloti, Hotiri, ati Mahasioti. Ọmọ Hemani, aríran ọba, ni gbogbo wọn, gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí Ọlọrun ṣe láti gbé Hemani ga; Ọlọrun fún un ní ọmọkunrin mẹrinla ati ọmọbinrin mẹta. Gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ ni wọ́n máa ń lu aro ati hapu, tí wọ́n sì ń tẹ dùùrù lábẹ́ àkóso baba wọn ninu ìsìn ninu ilé Ọlọrun. Ṣugbọn Asafu, Jedutuni, ati Hemani wà lábẹ́ àkóso ọba. Àpapọ̀ wọn pẹlu àwọn arakunrin wọn, tí a ti kọ́ ní orin kíkọ sí OLUWA, ati lílo ohun èlò orin, jẹ́ ọọdunrun ó dín mejila (288). Gègé ni wọ́n ṣẹ́ tí wọ́n fi mọ iṣẹ́ olukuluku; ati kékeré ati àgbà, ati olùkọ́ ati akẹ́kọ̀ọ́. Gègé kinni tí wọ́n ṣẹ́ fún ìdílé Asafu mú Josẹfu; ekeji mú Gedalaya, òun ati àwọn arakunrin rẹ̀ ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin jẹ́ mejila. Ẹkẹta mú Sakuri, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. Ẹkẹrin mú Isiri, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. Ẹkarun-un mú Netanaya, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. Ẹkẹfa mú Bukaya, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. Ekeje mú Jeṣarela, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. Ẹkẹjọ mú Jeṣaya, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. Ẹkẹsan-an mú Matanaya, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. Ẹkẹwaa mú Ṣimei, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. Ikọkanla mú Asareli, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. Ekejila mú Haṣabaya, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. Ẹkẹtala mú Ṣubaeli, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. Ẹkẹrinla mú Matitaya, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. Ẹkẹẹdogun mú Jeremotu, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. Ẹkẹrindinlogun mu Hananaya, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. Ẹkẹtadinlogun mú Joṣibekaṣa, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. Ekejidinlogun mú Hanani, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. Ikọkandinlogun mú Maloti, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. Gègé ogún mú Eliata, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. Ikọkanlelogun mú Hotiri, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. Ekejilelogun mú Gidaliti, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. Ẹkẹtalelogun mú Mahasioti, òun ati àwọn ọmọkunrin rẹ̀, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. Ẹkẹrinlelogun mú Romamiti Eseri, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. Bí a ti ṣe pín iṣẹ́ fún àwọn aṣọ́nà nìwọ̀nyí: Meṣelemaya, ọmọ Kore, ní ìdílé Asafu, ninu ìran Kora. Meṣelemaya bí ọmọ meje, orúkọ wọn nìyí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí wọn, Sakaraya ni àkọ́bí, lẹ́yìn náà Jediaeli, Sebadaya, ati Jatinieli; Elamu, Jehohanani ati Eliehoenai. Ọmọ mẹjọ ni Obedi Edomu bí nítorí pé Ọlọrun bukun un. Orúkọ àwọn ọmọ náà nìyí, bẹ̀rẹ̀ láti orí àkọ́bí: Ṣemaaya, Jehosabadi, ati Joa; Sakari, ati Netaneli; Amieli, Isakari, ati Peuletai. Ṣemaaya, àkọ́bí Obedi Edomu, bí ọmọ mẹfa, àwọn ni olórí ninu ìdílé wọn nítorí pé alágbára eniyan ni wọ́n. Orúkọ wọn ni: Otini, Refaeli, Obedi, ati Elisabadi, ati àwọn arakunrin wọn, Elihu ati Semakaya, tí wọ́n jẹ́ alágbára eniyan. Gbogbo àwọn arọmọdọmọ Obedi Edomu, ati àwọn ọmọ wọn, pẹlu àwọn arakunrin wọn, tí wọ́n yẹ láti ṣiṣẹ́ jẹ́ mejilelọgọta. Àwọn ọmọ Meṣelemaya ati àwọn arakunrin rẹ̀ tí wọ́n lágbára jẹ́ mejidinlogun. Hosa, láti inú ìran Merari bí ọmọkunrin mẹrin: Ṣimiri (ni baba rẹ̀ fi ṣe olórí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe òun ni àkọ́bí); lẹ́yìn rẹ̀ Hilikaya, Tebalaya ati Sakaraya. Gbogbo àwọn ọmọ Hosa ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mẹtala. Gbogbo àwọn aṣọ́nà tẹmpili ni a pín sí ẹgbẹẹgbẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn. A pín iṣẹ́ fún àwọn náà gẹ́gẹ́ bí a ti pín iṣẹ́ fún àwọn arakunrin wọn yòókù tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ninu ilé OLUWA. Gègé ni wọ́n ṣẹ́ fún ìdílé kọ̀ọ̀kan, láti mọ ẹnu ọ̀nà tí wọn yóo máa ṣọ́, wọn ìbáà jẹ́ eniyan yẹpẹrẹ, wọn ìbáà sì jẹ́ eniyan pataki. Ṣelemaya ni gègé mú fún ẹnu ọ̀nà tí ó wà ní apá ìlà oòrùn. Sakaraya, ọmọ rẹ̀, olùdámọ̀ràn tí ó mòye, ni gègé mú fún ẹnu ọ̀nà ti ìhà àríwá. Obedi Edomu ni gègé mú fún ẹnu ọ̀nà ti ìhà gúsù; àwọn ọmọ rẹ̀ ni a sì yàn láti máa ṣọ́ ilé ìṣúra. Gègé mú Ṣupimu ati Hosa fún ẹnu ọ̀nà apá ìwọ̀ oòrùn ati ẹnu ọ̀nà Ṣaleketi, ní ojú ọ̀nà tí ó lọ sí òkè. Olukuluku àwọn aṣọ́nà ni ó ní àkókò iṣẹ́ tirẹ̀. Àwọn eniyan mẹfa ni wọ́n ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà apá ìwọ̀ oòrùn ní ojoojumọ, àwọn mẹrin ń ṣọ́ ìhà àríwá, àwọn mẹrin ń ṣọ́ ìhà gúsù, àwọn meji meji sì ń ṣọ́ ilé ìṣúra. Fún àgọ́ tí ó wà ní ìwọ̀ oòrùn, àwọn mẹrin ń ṣọ́ ojú ọ̀nà, àwọn meji sì ń ṣọ́ àgọ́ alára. Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe pín iṣẹ́ fún àwọn aṣọ́nà láti inú ìran Kora ati ti Merari. Ahija, láti inú ẹ̀yà Lefi, ni ó ń bojútó àwọn ibi ìṣúra tí ó wà ninu ilé OLUWA ati ibi tí wọn ń kó àwọn ẹ̀bùn tí a yà sọ́tọ̀ fún Ọlọrun sí. Ladani, ọ̀kan ninu ìran Geriṣoni, ní àwọn ọmọkunrin tí wọ́n jẹ́ olórí ìdílé wọn, ọ̀kan ninu wọn ń jẹ́ Jehieli. Àwọn ọmọ Jehieli meji: Setamu ati Joẹli ni wọ́n ń bojútó àwọn ibi ìṣúra tí ó wà ninu ilé OLUWA. A pín iṣẹ́ fún àwọn ọmọ Amramu, ati àwọn ọmọ Iṣari, ati àwọn ọmọ Heburoni ati àwọn ọmọ Usieli. Ṣebueli, ọmọ Geriṣomu, láti inú ìran Mose, ni olórí àwọn tí ń bojútó ibi ìṣúra. Ninu àwọn arakunrin Ṣebueli, láti ìdílé Elieseri, a yan Rehabaya ọmọ Elieseri, Jeṣaaya ọmọ Rehabaya, Joramu ọmọ Jeṣaaya, Sikiri ọmọ Joramu ati Ṣelomiti ọmọ Sikiri. Ṣelomiti yìí ati àwọn arakunrin rẹ̀ ni wọ́n ń bojútó àwọn ẹ̀bùn tí Dafidi ọba, ati ti àwọn olórí àwọn ìdílé, ati èyí tí àwọn olórí ọmọ ogun ẹgbẹẹgbẹrun ati ọgọọgọrun-un, ti yà sọ́tọ̀ fún Ọlọrun. Ninu àwọn ìkógun tí wọ́n kó lójú ogun, wọ́n ya àwọn ẹ̀bùn kan sọ́tọ̀ fún ìtọ́jú ilé OLUWA. Ṣelomiti ati àwọn arakunrin rẹ̀ ni wọ́n ń ṣe ìtọ́jú ẹ̀bùn tí àwọn eniyan bá mú wá, ati àwọn ohun tí wolii Samuẹli, ati Saulu ọba, ati Abineri, ọmọ Neri, ati Joabu, ọmọ Seruaya, ti yà sọ́tọ̀ ninu ilé OLUWA. Ninu ìdílé Iṣari, Kenanaya ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni wọ́n yàn ní alákòóso ati onídàájọ́ fún àwọn ọmọ Israẹli. Ninu ìdílé Heburoni, Haṣabaya ati ẹẹdẹgbẹsan (1,700) àwọn arakunrin rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ alágbára ni wọ́n ń bojútó àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani, tí wọn ń ṣe iṣẹ́ OLUWA ati iṣẹ́ ọba, Ninu ìdílé Heburoni, Jerija ni baba ńlá gbogbo wọn. (Ní ogoji ọdún tí Dafidi dé orí oyè, wọ́n ṣe ìwádìí nípa ìran Heburoni, wọ́n sì rí àwọn ọkunrin tí wọ́n lágbára ninu ìran wọn ní Jaseri ní agbègbè Gileadi). Dafidi ọba, yan òun ati àwọn arakunrin rẹ̀, tí gbogbo wọn jẹ́ ẹgbaa ó lé ẹẹdẹgbẹrin (2,700) alágbára, láti jẹ́ alámòójútó àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ati ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase nípa gbogbo nǹkan tí ó jẹ mọ́ ti Ọlọrun ati àwọn nǹkan tó jẹ́ ti ọba. Àwọn wọnyi ni àwọn olórí ìdílé ati olórí ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun ati olórí ọgọọgọrun-un ọmọ ogun, ati àwọn olórí tí wọ́n jẹ́ aṣojú ọba ní gbogbo ìpínlẹ̀ ní oṣooṣù, títí ọdún yóo fi yípo ni wọn máa ń yan ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000) eniyan, tí wọn ń pààrọ̀ ara wọn. Jaṣobeamu, ọmọ Sabidieli, ni olórí ìpín kinni, fún oṣù kinni; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji. Ìran Peresi ni Jaṣobeamu, òun sì ni balogun fún gbogbo àwọn ọ̀gágun fún oṣù kinni. Dodai, láti inú ìran Ahohi, ni olórí ìpín ti oṣù keji, iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000). Balogun kẹta, tí ó wà fún oṣù kẹta ni Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, alufaa. Iye àwọn tí ó wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000). Bẹnaya yìí jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ọgbọ̀n akọni jagunjagun, òun sì ni olórí wọn. Amisabadi ọmọ rẹ̀ ni ó ń ṣe àkóso ìpín rẹ̀. Asaheli, arakunrin Joabu, ni balogun fún oṣù kẹrin. Sebadaya, ọmọ rẹ̀, ni igbákejì rẹ̀. Iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000). Balogun tí ó wà fún oṣù karun-un ni Ṣamuhutu, láti inú ìran Iṣari; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000). Balogun tí ó wà fún oṣù kẹfa ni Ira, ọmọ Ikeṣi ará Tekoa; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000). Balogun tí ó wà fún oṣù keje ni Helesi, ará Peloni, láti inú ẹ̀yà Efuraimu; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000). Balogun tí ó wà fún oṣù kẹjọ ni Sibekai, ará Huṣa, láti inú ìran Serahi; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000). Balogun tí ó wà fún oṣù kẹsan-an ni Abieseri ará Anatoti, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini. Iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000). Balogun tí ó wà fún oṣù kẹwaa ni Maharai, ará Netofa láti inú ìran Serahi; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000). Balogun tí ó wà fún oṣù kọkanla ni Bẹnaya, ará Piratoni, láti inú ẹ̀yà Efuraimu; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000). Balogun tí ó wà fún oṣù kejila ni Helidai ará Netofati, láti inú ìran Otinieli; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000). Àwọn tí wọ́n jẹ́ olórí ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli nìwọ̀nyí, láti inú ẹ̀yà Reubẹni: Elieseri, ọmọ Sikiri ni olórí patapata. Láti inú ẹ̀yà Simeoni: Ṣefataya, ọmọ Maaka. Láti inú ẹ̀yà Lefi: Haṣabaya, ọmọ Kemueli; láti ìdílé Aaroni: Sadoku; láti inú ẹ̀yà Juda: Elihu, ọ̀kan ninu àwọn arakunrin Dafidi; láti inú ẹ̀yà Isakari: Omiri, ọmọ Mikaeli; láti inú ẹ̀yà Sebuluni: Iṣimaya, ọmọ Ọbadaya; láti inú ẹ̀yà Nafutali: Jeremotu, ọmọ Asirieli; láti inú ẹ̀yà Efuraimu: Hoṣea, ọmọ Asasaya; láti inú ìdajì ẹ̀yà Manase: Joẹli, ọmọ Pedaya; láti inú ìdajì ẹ̀yà Manase tí ó wà ní Gileadi: Ido, ọmọ Sakaraya; láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini: Jaasieli, ọmọ Abineri; láti inú ẹ̀yà Dani: Asareli, ọmọ Jerohamu. Àwọn ni olórí àwọn ẹ̀yà Israẹli. Dafidi kò ka àwọn tí wọn kò tó ọmọ ogún ọdún, nítorí Ọlọrun ti ṣe ìlérí pé òun yóo mú kí àwọn ọmọ Israẹli pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run. Joabu, ọmọ Seruaya, bẹ̀rẹ̀ sí ka àwọn eniyan, ṣugbọn kò parí rẹ̀. Sibẹsibẹ ibinu OLUWA wá sórí Israẹli nítorí rẹ̀; nítorí náà, kò sí àkọsílẹ̀ fún iye àwọn ọmọ Israẹli ninu ìwé ìtàn ọba Dafidi. Àwọn tí ń ṣe àkóso àwọn ohun ìní ọba nìwọ̀nyí: Asimafeti, ọmọ Adieli, ni alabojuto àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ní ààfin ọba. Jonatani, ọmọ Usaya, ni ó wà fún àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ninu àwọn ìlú kéékèèké, àwọn ìlú ńláńlá, àwọn ìletò ati àwọn ilé ìṣọ́. Esiri, ọmọ Kelubu, ni alabojuto fún gbogbo iṣẹ́ oko dídá. Ṣimei, ará Rama, ni ó wà fún àwọn ọgbà àjàrà. Sabidi, ará Ṣifimu, ni ó wà fún ibi tí wọ́n ti ń pọn ọtí. Baali Hanani, ará Gederi, ni ó wà fún àwọn ọgbà olifi ati ti igi sikamore. Joaṣi ni ó wà fún ibi tí wọ́n ń kó òróró olifi pamọ́ sí. Ṣitirai, ará Ṣaroni, ni ó wà fún àwọn agbo mààlúù tí wọ́n wà ní Ṣaroni. Ṣafati, ọmọ Adila, ni ó wà fún àwọn agbo mààlúù tí wọ́n wà ní àwọn àfonífojì. Obili, ará Iṣmaeli, ni ó wà fún àwọn ràkúnmí. Jedeaya, ará Meronoti, ni ó wà fún àwọn abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Jasisi, ará Hagiri, sì jẹ́ alabojuto àwọn agbo aguntan. Gbogbo wọn jẹ́ alabojuto àwọn ohun ìní Dafidi ọba. Jonatani, arakunrin baba Dafidi ọba, ni olùdámọ̀ràn nítorí pé ó ní òye, ó sì tún jẹ́ akọ̀wé. Òun ati Jehieli, ọmọ Hakimoni, ní ń ṣe àmójútó àwọn ọmọ ọba. Ahitofeli jẹ́ olùdámọ̀ràn fún ọba, Huṣai ará Ariki sì ni ọ̀rẹ́ ọba. Lẹ́yìn ikú Ahitofeli, Jehoiada, ọmọ Bẹnaya ati Abiatari di olùdámọ̀ràn ọba. Joabu sì jẹ́ balogun ọba. Dafidi ọba pe gbogbo àwọn olórí ní ilẹ̀ Israẹli jọ sí Jerusalẹmu, àwọn olórí láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli, àwọn olórí àwọn ìpín tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ fún ọba, àwọn ọ̀gágun ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun, ati ọgọọgọrun-un ọmọ ogun, gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ alabojuto ohun ìní ati ẹran ọ̀sìn ọba, àwọn tí wọ́n ń tọ́jú àwọn ọmọ ọba, àwọn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní ààfin, àwọn eniyan pataki pataki ati àwọn akọni ọmọ ogun, gbogbo wọn péjọ sí Jerusalẹmu. Dafidi bá dìde dúró, ó ní, “Ẹ gbọ́ mi, ẹ̀yin ará mi ati eniyan mi, mo ní i lọ́kàn láti kọ́ ilé ìsinmi fún Àpótí Majẹmu OLUWA, ati fún àpótí ìtìsẹ̀ Ọlọrun wa; mo ti tọ́jú gbogbo nǹkan sílẹ̀, mo sì ti múra tán. Ṣugbọn, Ọlọrun sọ fún mi pé, kì í ṣe èmi ni n óo kọ́ ilé fún òun, nítorí pé jagunjagun ni mí, mo sì ti ta ẹ̀jẹ̀ pupọ sílẹ̀. Sibẹsibẹ OLUWA Ọlọrun Israẹli yàn mí ninu ilé baba mi láti jọba lórí Israẹli títí lae; nítorí pé ó yan ẹ̀yà Juda láti ṣe aṣaaju Israẹli. Ninu ẹ̀yà Juda, ó yan ilé baba mi, láàrin àwọn ọmọ baba mi, ó ní inú dídùn sí mi, ó fi mí jọba lórí gbogbo Israẹli. OLUWA fún mi ní ọmọ pupọ, ṣugbọn ninu gbogbo wọn, ó yan Solomoni láti jọba lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ lórí Israẹli. “OLUWA sọ fún mi pé, ‘Solomoni, ọmọ rẹ ni yóo kọ́ ilé mi ati àgbàlá mi, nítorí mo ti yàn án láti jẹ́ ọmọ mi, èmi yóo sì jẹ́ baba fún un. N óo fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ títí lae, bí ó bá ti pinnu láti máa pa òfin ati ìlànà mi mọ́, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe nisinsinyii.’ “Nítorí náà, lójú gbogbo ọmọ Israẹli, lójú ìjọ eniyan OLUWA, ati ní etígbọ̀ọ́ Ọlọrun wa, mò ń kìlọ̀ fun yín pé kí ẹ máa pa gbogbo òfin OLUWA Ọlọrun yín mọ́, kí ẹ̀yin ati arọmọdọmọ yín baà lè máa gbé ilẹ̀ yìí títí lae. “Ìwọ Solomoni, ọmọ mi, mọ Ọlọrun àwọn baba rẹ, kí o sì fi gbogbo ọkàn rẹ sìn ín tìfẹ́tìfẹ́, nítorí OLUWA a máa wádìí ọkàn, ó sì mọ gbogbo èrò ati ète eniyan. Bí o bá wá OLUWA, o óo rí i, ṣugbọn bí o bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, yóo ta ọ́ nù títí lae. Kíyèsára, nítorí pé OLUWA ti yàn ọ́ láti kọ́ ilé kan tí yóo jẹ́ ibi mímọ́, ṣe gírí, kí o sì kọ́ ọ.” Dafidi bá fún Solomoni ní àwòrán tẹmpili náà tí wọ́n fi ọwọ́ yà, ati ti àwọn ilé mìíràn tí yóo kọ́ mọ́ tẹmpili, ati ti àwọn ilé ìṣúra rẹ̀, àwọn yàrá òkè, àwọn yàrá ti inú, ati ti yàrá ìtẹ́ àánú; ati àwòrán gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn láti ṣe sinu àgbàlá ilé OLUWA, ati ti àwọn yàrá káàkiri, àwọn ilé ìṣúra tí yóo wà ninu ilé Ọlọrun, ati ti àwọn ilé ìṣúra tí wọ́n o máa kó ohun tí a yà sọ́tọ̀ fún OLUWA pamọ́ sí. Dafidi tún fún un ní ìwé ètò pípín àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, ati ètò gbogbo iṣẹ́ ìsìn inú ilé OLUWA, ti àwọn ohun èlò fún ìsìn ninu ilé OLUWA; àkọsílẹ̀ ìwọ̀n wúrà fún gbogbo ohun èlò wúrà fún ìsìn kọ̀ọ̀kan, ti ìwọ̀n fadaka fún gbogbo ohun èlò fadaka fún ìsìn kọ̀ọ̀kan, ti ìwọ̀n àwọn ọ̀pá fìtílà wúrà ati àwọn fìtílà wọn, ti ìwọ̀n fadaka fún ọ̀pá fìtílà kan ati àwọn fìtílà wọn, gẹ́gẹ́ bí ìlò olukuluku wọn ninu ìsìn. Ètò ìwọ̀n wúrà fún tabili àkàrà ìfihàn kọ̀ọ̀kan ati ìwọ̀n fadaka fún tabili fadaka kọ̀ọ̀kan, ìwọ̀n ojúlówó wúrà fún àwọn àmúga tí a fi ń mú ẹran, àwọn agbada, àwọn ife, àwọn abọ́ wúrà ati ti ìwọ̀n abọ́ fadaka kọ̀ọ̀kan, ìwọ̀n pẹpẹ turari tí a fi wúrà yíyọ́ ṣe ati ohun tí ó ní lọ́kàn nípa àwọn kẹ̀kẹ́ wúrà àwọn Kerubu tí wọ́n na ìyẹ́ wọn bo Àpótí Majẹmu OLUWA. Gbogbo nǹkan wọnyi ni ó kọ sílẹ̀ fínnífínní gẹ́gẹ́ bí ìlànà láti ọ̀dọ̀ OLUWA nípa iṣẹ́ inú tẹmpili; ó ní gbogbo rẹ̀ ni wọ́n sì gbọdọ̀ ṣe gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ náà. Dafidi bá sọ fún Solomoni, ọmọ rẹ̀ pé, “Múra gírí, mú ọkàn le, kí o sì ṣe bí mo ti wí. Má bẹ̀rù, má sì jẹ́ kí ọkàn rẹ rẹ̀wẹ̀sì; nítorí OLUWA Ọlọrun, àní Ọlọrun mi, wà pẹlu rẹ. Kò ní já ọ kulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní kọ̀ ọ́ sílẹ̀, títí tí iṣẹ́ ilé OLUWA yóo fi parí. Gbogbo ètò iṣẹ́ ati pípín àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi ninu tẹmpili ni a ti ṣe fínnífínní. Àwọn tí wọ́n mọ oríṣìíríṣìí iṣẹ́ yóo wà pẹlu rẹ, bákan náà, àwọn olórí ati gbogbo eniyan Israẹli yóo wà lábẹ́ àṣẹ rẹ.” Dafidi ọba sọ fún àpéjọpọ̀ àwọn eniyan pé, “Solomoni ọmọ mi, ẹnìkan ṣoṣo tí Ọlọrun yàn, ó kéré, kò tíì ní ìrírí, iṣẹ́ náà sì tóbi pupọ, nítorí ààfin náà kò ní wà fún eniyan, bíkòṣe fún OLUWA Ọlọrun. Mo ti sa ipá tèmi láti pèsè oríṣìíríṣìí nǹkan sílẹ̀ fún ilé OLUWA: wúrà fún àwọn ohun tí a nílò wúrà fún, fadaka fún àwọn ohun tí a nílò fadaka fún, idẹ fún àwọn ohun tí a nílò idẹ fún, irin fún àwọn ohun tí a nílò irin fún, pákó fún àwọn ohun tí a nílò pákó fún, lẹ́yìn náà, òkúta ìkọ́lé, òkúta olówó iyebíye, àwọn òkúta tí ó ní oríṣìíríṣìí àwọ̀, ati mabu. Lẹ́yìn náà, yàtọ̀ fún gbogbo àwọn nǹkan tí mo ti pèsè fún Tẹmpili Ọlọrun mi, mo ní ilé ìṣúra ti èmi alára, tí ó kún fún wúrà ati fadaka, ṣugbọn nítorí ìfẹ́ mi sí ilé Ọlọrun mi, mo fi wọ́n sílẹ̀ fún iṣẹ́ ilé náà. Mo ti pèsè ẹgbẹẹdogun (3,000) ìwọ̀n talẹnti wúrà dáradára láti ilẹ̀ Ofiri, ati ẹẹdẹgbaarin (7,000) ìwọ̀n talẹnti fadaka tí a ti yọ́, láti fi bo gbogbo ògiri tẹmpili náà, ati àwọn ohun èlò mìíràn tí àwọn oníṣẹ́ ọnà yóo lò: wúrà fún àwọn ohun èlò wúrà, ati fadaka fún àwọn ohun èlò fadaka. Nisinsinyii, ninu yín, ta ló fẹ́ fi tinútinú ṣe ìtọrẹ, tí yóo sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ lónìí fún OLUWA?” Nígbà náà ni àwọn olórí àwọn ìdílé, àwọn olórí àwọn ẹ̀yà Israẹli, àwọn ọ̀gágun ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun ati ti ọgọọgọrun-un ọmọ ogun, ati àwọn alabojuto ohun ìní ọba, bẹ̀rẹ̀ sí dá ọrẹ àtinúwá jọ. Àwọn nǹkan tí wọ́n fi sílẹ̀ fún iṣẹ́ ilé OLUWA nìwọ̀nyí: ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) talẹnti wúrà, ẹgbaarun (10,000) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ẹgbaasan-an (18,000) ìwọ̀n talẹnti idẹ ati ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) ìwọ̀n talẹnti irin. Gbogbo àwọn tí wọ́n ní òkúta olówó iyebíye ni wọ́n mú wọn wá tí wọ́n fi wọ́n sí ibi ìṣúra ilé OLUWA, tí ó wà lábẹ́ àbojútó Jehieli ará Geriṣoni. Inú àwọn eniyan náà dùn pé wọ́n fi tinútinú mú ọrẹ wá nítorí pé tọkàntọkàn ati tìfẹ́tìfẹ́ ni wọ́n fi mú ọrẹ wá fún OLUWA; inú Dafidi ọba náà sì dùn pupọ pẹlu. Nítorí náà, Dafidi yin OLUWA níwájú gbogbo eniyan, ó ní: “Ìyìn ni fún ọ títí lae, OLUWA, Ọlọrun Israẹli, Baba ńlá wa, OLUWA, o tóbi pupọ, tìrẹ ni agbára, ògo, ìṣẹ́gun, ati ọlá ńlá; nítorí tìrẹ ni ohun gbogbo ní ọ̀run ati ní ayé. Tìrẹ ni ìjọba, a gbé ọ ga bí orí fún ohun gbogbo. Láti ọ̀dọ̀ rẹ wá ni ọrọ̀ ati ọlá ti ń wá, o sì ń jọba lórí ohun gbogbo. Ìkáwọ́ rẹ ni ipá ati agbára wà, ó wà ní ìkáwọ́ rẹ láti gbéni ga ati láti fún ni lágbára. A dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Ọlọrun wa, a sì yin orúkọ rẹ tí ó lógo. “Ṣugbọn, kí ni mo jẹ́, kí sì ni àwọn eniyan mi jẹ́, tí a fi lè mú ọrẹ tí ó pọ̀ tó báyìí wá fún Ọlọrun tọkàntọkàn? Nítorí láti ọ̀dọ̀ rẹ ni ohun gbogbo ti wá, ninu ohun tí o fún wa ni a sì ti mú wá fún ọ. Àjèjì ati àlejò ni a jẹ́ ní ojú rẹ, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba ńlá wa. Gbogbo ọjọ́ wa láyé dàbí òjìji, kò lè wà pẹ́ títí. OLUWA, Ọlọrun wa, tìrẹ ni gbogbo ohun tí a mú wá, láti fi kọ́ ilé fún orúkọ mímọ́ rẹ, ọ̀dọ̀ rẹ ni wọ́n sì ti wá. Ọlọrun mi, mo mọ̀ pé ò máa yẹ ọkàn wò, o sì ní inú dídùn sí òtítọ́; tọkàntọkàn mi ni mo fi mú gbogbo nǹkan wọnyi wá fún ọ, mo sì ti rí i bí àwọn eniyan rẹ ti fi tọkàntọkàn ati inú dídùn mú ọrẹ wọn wá fún ọ. OLUWA Ọlọrun àwọn baba wa: Abrahamu, Isaaki ati Israẹli, jẹ́ kí irú ẹ̀mí yìí túbọ̀ máa wà ninu àwọn eniyan rẹ títí lae, kí o sì jẹ́ kí ọkàn wọn máa fà sí ọ̀dọ̀ rẹ. Jọ̀wọ́, jẹ́ kí Solomoni ọmọ mi, fi gbogbo ọkàn rẹ̀ pa òfin, àṣẹ ati ìlànà rẹ mọ́, kí ó lè ṣe ohun gbogbo, kí ó sì lè kọ́ tẹmpili tí mo ti múra rẹ̀ sílẹ̀ fún.” Dafidi sọ fún gbogbo ìjọ eniyan pé, “Ẹ yin OLUWA Ọlọrun yín.” Gbogbo wọn bá yin OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn. Wọ́n wólẹ̀, wọ́n sin OLUWA, wọ́n sì tẹríba fún ọba. Ní ọjọ́ keji, wọ́n fi ẹgbẹrun akọ mààlúù rú ẹbọ sísun sí OLUWA, ati ẹgbẹrun àgbò, ati ẹgbẹrun ọ̀dọ́ aguntan, pẹlu ọrẹ ohun mímu ati ọpọlọpọ ẹbọ fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n jẹ, wọ́n sì mu níwájú Ọlọrun ní ọjọ́ náà pẹlu ayọ̀ ńlá. Wọ́n tún fi Solomoni, ọmọ Dafidi, jẹ ọba lẹẹkeji. Wọ́n fi òróró yàn án ní ọba ní orúkọ OLUWA, Sadoku sì ni alufaa. Solomoni jókòó lórí ìtẹ́ OLUWA gẹ́gẹ́ bí ọba, dípò Dafidi, baba rẹ̀. Solomoni ní ìlọsíwájú, gbogbo àwọn eniyan Israẹli sì ń gbọ́ tirẹ̀. Gbogbo àwọn ìjòyè, àwọn alágbára, ati gbogbo àwọn ọmọ Dafidi ọba ni wọ́n jẹ́jẹ̀ẹ́ láti máa gbọ́ ti Solomoni. OLUWA gbé Solomoni ga lójú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ó sì fún un ní ọlá ju gbogbo àwọn ọba tí wọ́n ti jẹ ṣáájú rẹ̀ ní Israẹli. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi, ọmọ Jese, ṣe jọba lórí gbogbo Israẹli. Ó jọba fún ogoji ọdún; ó jọba fún ọdún meje ní Heburoni, ó sì jọba fún ọdún mẹtalelọgbọn ní Jerusalẹmu. Ẹ̀mí rẹ̀ gùn, ó lọ́rọ̀, ó sì lọ́lá, ó sì di arúgbó kàngẹ́kàngẹ́ kí ó tó kú, Solomoni ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Ìtàn ìgbé ayé ọba Dafidi láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin ni a kọ sí inú ìwé ìtàn tí wolii Samuẹli kọ, èyí tí wolii Natani kọ, ati èyí tí wolii Gadi kọ. Àkọsílẹ̀ yìí sọ bí ó ti ṣe ìjọba rẹ̀, bí agbára rẹ̀ ti tó; ati gbogbo nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀ sí i, ati èyí tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ Israẹli ati sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà ní àyíká wọn. Solomoni, ọmọ Dafidi, fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀, OLUWA Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀, ó sì sọ ọ́ di ẹni ńlá. Solomoni bá gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀: àwọn balogun ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun ati ti ọgọọgọrun-un ọmọ ogun, àwọn adájọ́, àwọn olórí ní Israẹli ati àwọn baálé baálé. Solomoni ati àwọn tí wọ́n péjọ lọ sí ibi gíga tí ó wà ní Gibeoni, nítorí pé àgọ́ ìpàdé Ọlọrun tí Mose, iranṣẹ OLUWA, pa ninu aginjù wà níbẹ̀. Ṣugbọn Dafidi ti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọrun wá láti Kiriati Jearimu sinu àgọ́ tí ó pa fún un ní Jerusalẹmu. Pẹpẹ bàbà tí Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri ṣe, wà níbẹ̀ níwájú àgọ́ OLUWA. Solomoni ati àwọn eniyan rẹ̀ sin OLUWA níbẹ̀. Ó lọ sí ìdí pẹpẹ bàbà tí ó wà níwájú OLUWA ninu àgọ́ àjọ, ó sì fi ẹgbẹrun (1,000) ẹran rú ẹbọ sísun lórí rẹ̀. Ní òru ọjọ́ náà, Ọlọrun fara han Solomoni, ó wí fún un pé “Bèèrè ohun tí o bá fẹ́ kí n fún ọ.” Solomoni dá Ọlọrun lóhùn, ó ní “O ti fi ìfẹ́ ńlá tí kìí yẹ̀ han Dafidi, baba mi, o sì ti fi mí jọba nípò rẹ̀. OLUWA, Ọlọrun, mú ìlérí tí o ṣe fún Dafidi, baba mi, ṣẹ nisinsinyii, nítorí pé o ti fi mí jọba lórí àwọn eniyan tí wọ́n pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀. Fún mi ní ọgbọ́n ati ìmọ̀ tí n óo fi máa ṣe àkóso àwọn eniyan wọnyi, nítorí pé ó ṣòro fún ẹnikẹ́ni láti ṣe àkóso àwọn eniyan rẹ tí wọ́n pọ̀ tó báyìí.” Ọlọrun dá Solomoni lóhùn pé, “Nítorí pé irú èrò yìí ló wà lọ́kàn rẹ, ati pé o kò sì tọrọ nǹkan ìní, tabi ọrọ̀, ọlá, tabi ẹ̀mí àwọn ọ̀tá rẹ, o kò tilẹ̀ tọrọ ẹ̀mí gígùn, ṣugbọn ọgbọ́n ati ìmọ̀ ni o tọrọ, láti máa ṣe àkóso àwọn eniyan mi tí mo fi ọ́ jọba lé lórí, n óo fún ọ ní ọgbọ́n ati ìmọ̀; n óo sì fún ọ ní ọrọ̀, nǹkan ìní, ati ọlá, irú èyí tí ọba kankan ninu àwọn tí wọ́n ti jẹ ṣiwaju rẹ kò tíì ní rí, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní sí èyí tí yóo jẹ lẹ́yìn rẹ tí yóo ní irú rẹ̀.” Solomoni kúrò ní àgọ́ ìpàdé tí ó wà ní ibi ìrúbọ ní Gibeoni, ó wá sí Jerusalẹmu, ó sì jọba lórí Israẹli. Solomoni kó kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin jọ; àwọn kẹ̀kẹ́ ogun jẹ́ egbeje (1,400) àwọn ẹlẹ́ṣin sì jẹ́ ẹgbaafa (12,000); ó kó wọn sí àwọn ìlú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ati sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ ní Jerusalẹmu. Fadaka ati wúrà tí ọba kójọ, pọ̀ bíi òkúta ní Jerusalẹmu, igi kedari sì pọ̀ bí igi sikamore tí ó wà ní Ṣefela, ní ẹsẹ̀ òkè Juda. Láti Ijipti ati Kue ni Solomoni ti ń kó ẹṣin wá, àwọn oníṣòwò tí wọn ń ṣiṣẹ́ fún un ni wọ́n ń ra àwọn ẹṣin náà wá láti Kue. Àwọn oníṣòwò a máa ra kẹ̀kẹ́ ogun kan ni ẹgbẹta (600) ìwọ̀n ṣekeli fadaka wá fún Solomoni láti Ijipti, wọn a sì máa ra ẹṣin kan ní aadọjọ (150) ìwọ̀n ṣekeli fadaka. Àwọn náà ni wọ́n sì ń bá a tà wọ́n fún àwọn ọba ilẹ̀ Hiti ati ti ilẹ̀ Siria. Solomoni ọba pinnu láti kọ́ tẹmpili níbi tí àwọn eniyan yóo ti máa sin OLUWA ati láti kọ́ ààfin fún ara rẹ̀. Ó kó ọ̀kẹ́ mẹta ati ẹgbaarun (70,000) àwọn òṣìṣẹ́ jọ láti máa ru àwọn nǹkan tí yóo fi kọ́lé, ọ̀kẹ́ mẹrin (80,000) àwọn òṣìṣẹ́ tí yóo máa fọ́ òkúta, ati ẹẹdẹgbaaji ó lé ẹgbẹta (3,600) eniyan láti máa bojútó àwọn òṣìṣẹ́. Solomoni ranṣẹ sí Huramu, ọba Tire pé, “Máa ṣe sí mi gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe sí Dafidi, baba mi, tí o kó igi kedari ranṣẹ sí i láti kọ́ ààfin rẹ̀. Mo fẹ́ kọ́ ilé ìsìn fún OLUWA Ọlọrun mi. Yóo jẹ́ ibi mímọ́ tí a ó ti máa sun turari olóòórùn dídùn níwájú rẹ̀. A ó máa mú ẹbọ àkàrà ojoojumọ lọ sibẹ, a ó sì máa rú ẹbọ sísun níbẹ̀ láàárọ̀ ati lálẹ́; ati ní ọjọọjọ́ ìsinmi, ati ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣooṣù, ati ní gbogbo ọjọ́ àjọ̀dún OLUWA Ọlọrun wa, gẹ́gẹ́ bí ó ti pa á láṣẹ fún Israẹli títí lae. Ilé tí mo fẹ́ kọ́ yóo tóbi pupọ, nítorí pé Ọlọrun wa tóbi ju gbogbo oriṣa lọ. Kò sí ẹni tí ó lè kọ́ ilé fún un, nítorí pé ọ̀run, àní ọ̀run tí ó ga jùlọ, kò le è gbà á. Kí ni mo jẹ́ tí n óo fi kọ́ ilé fún un, bíkòṣe pé kí n kọ́ ibi tí a óo ti máa sun turari níwájú rẹ̀? Nítorí náà, fi ẹnìkan ranṣẹ sí mi, tí ó mọ̀ nípa iṣẹ́ wúrà, fadaka, bàbà, ati irin, ẹni tí ó lè ṣiṣẹ́ ọnà sí ara aṣọ elése àlùkò, ati àlàárì, ati aṣọ aláwọ̀ aró, tí ó sì mọ̀ nípa iṣẹ́ gbẹ́nàgbẹ́nà. Yóo wà pẹlu àwọn òṣìṣẹ́ tí baba mi ti pèsè sílẹ̀, tí wọ́n wà pẹlu mi ní Juda ati Jerusalẹmu. Kó igi kedari, sipirẹsi ati aligumu ranṣẹ sí mi láti Lẹbanoni. Mo mọ̀ pé àwọn iranṣẹ rẹ mọ̀ bí wọ́n ṣe ń gé igi ní Lẹbanoni, àwọn iranṣẹ mi náà yóo sì wà pẹlu wọn, láti tọ́jú ọpọlọpọ igi, nítorí pé ilé tí mo fẹ́ kọ́ yóo tóbi, yóo sì jọjú. N óo gbé ọ̀kẹ́ kan (20,000) ìwọ̀n kori ọkà tí a ti lọ̀, ati ọ̀kẹ́ kan (20,000) ìwọ̀n baali, ati ọ̀kẹ́ kan (20,000) ìwọ̀n bati ọtí, ati ọ̀kẹ́ kan (20,000) ìwọ̀n bati òróró fún àwọn iranṣẹ rẹ tí wọn yóo gé àwọn igi náà, wọn óo gbé wọn wá fún ọ.” Huramu, ọba Tire, bá dá èsì lẹta Solomoni pada, ó ní, “OLUWA fẹ́ràn àwọn eniyan rẹ̀, ni ó ṣe fi ọ́ jọba lórí wọn.” Ó tún fi kún un pé, “Ìyìn ni fún OLUWA Ọlọrun Israẹli tí ó dá ọ̀run ati ayé, tí ó fún Dafidi ní ọmọ tí ó gbọ́n, tí ó sì ní òye ati ìmọ̀ láti kọ́ tẹmpili fún OLUWA ati láti kọ́ ààfin fún ara rẹ̀. Mo ti rán Huramu sí ọ; ó mọṣẹ́, ó sì ní làákàyè. Ará Dani ni ìyá rẹ̀, ṣugbọn ará Tire ni baba rẹ̀. Ó mọ iṣẹ́ àgbẹ̀dẹ wúrà, ati ti fadaka, ti bàbà, ati ti irin; ó sì mọ òkúta, ati igi í gbẹ́. Ó mọ bí a tií ṣe iṣẹ́ ọnà sí ara aṣọ elése àlùkò, aṣọ aláwọ̀ aró, àlàárì, ati aṣọ ọ̀gbọ̀ onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́. Ó lè ṣe iṣẹ́ gbẹ́nàgbẹ́nà, ó sì lè ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà tí wọ́n bá ní kí ó ṣe pẹlu àwọn òṣìṣẹ́ tìrẹ, ati àwọn òṣìṣẹ́ oluwa mi, Dafidi, baba rẹ. Nítorí náà, fi ọkà baali, òróró ati ọtí tí ìwọ oluwa mi ti ṣèlérí ranṣẹ sí èmi iranṣẹ rẹ. A óo gé gbogbo igi tí o bá nílò ní Lẹbanoni, a óo sì tù wọ́n lójú omi wá sí Jọpa, láti ibẹ̀ ni ẹ lè wá kó wọn lọ sí Jerusalẹmu.” Solomoni ka gbogbo àwọn àjèjì tí wọn ń gbé ilẹ̀ Israẹli gẹ́gẹ́ bí Dafidi baba rẹ̀ ti ṣe. Wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ meje, ó lé ẹgbaaje ati ẹgbẹta (153,600). Ó yan ọ̀kẹ́ mẹta ó lé ẹgbaarun (70,000) ninu wọn láti máa ru nǹkan ìkọ́lé, ó ní kí ọ̀kẹ́ mẹrin (80,000) eniyan máa la òkúta, kí ẹẹdẹgbaaji ó lé ẹgbẹta (3,600) jẹ́ alákòóso tí yóo máa kó wọn ṣiṣẹ́. Solomoni bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ tẹmpili OLUWA ní Jerusalẹmu, níbi ìpakà Onani, ará Jebusi, lórí òkè Moraya, níbi tí OLUWA ti fi ara han Dafidi, baba rẹ̀; Dafidi ti tọ́jú ibẹ̀ sílẹ̀ tẹ́lẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé náà ní ọjọ́ keji oṣù keji ọdún kẹrin ìjọba rẹ̀. Ìpìlẹ̀ ilé Ọlọrun tí Solomoni fi lélẹ̀ gùn ní ọgọta igbọnwọ (mita 27), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). Yàrá kan wà ní ẹnu ọ̀nà àbáwọlé tí ìbú rẹ̀ jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). Ó ga ní ọgọfa igbọnwọ (mita 54), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ déédé ìbú tẹmpili. Ó yọ́ ojúlówó wúrà bo gbogbo inú rẹ̀. Ó fi igi sipirẹsi tẹ́ gbogbo inú gbọ̀ngàn rẹ̀. Ó sì yọ́ wúrà dáradára bò ó lórí, ó ya igi ọ̀pẹ ati ẹ̀wọ̀n, ó fi dárà sórí rẹ̀. Ó fi òkúta olówó iyebíye ṣe iṣẹ́ ọnà sára ilé náà, wúrà tí ó rà wá láti ilẹ̀ Pafaimu ni ó lò. Ó yọ́ wúrà bo gbogbo igi àjà ilé náà patapata, ati àwọn òpó rẹ̀, ati àwọn ẹnu ọ̀nà rẹ̀, ògiri rẹ̀ ati àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀; ó sì fi àwòrán àwọn kerubu dárà sí ara àwọn ògiri. Ó kọ́ ibi mímọ́ jùlọ, gígùn rẹ̀ ṣe déédé ìbú tẹmpili náà, ó gùn ní ogún igbọnwọ (mita 9). Ìbú rẹ̀ náà sì jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). Ó yọ́ ìwọ̀n ẹgbẹta (600) talẹnti ojúlówó wúrà, ó fi bo gbogbo inú rẹ̀. Aadọta ìwọ̀n ṣekeli wúrà ni ó fi ṣe ìṣó, ó sì yọ́ wúrà bo gbogbo ara ògiri yàrá òkè. Ó fi igi gbẹ́ kerubu meji, ó yọ́ wúrà bò wọ́n, ó sì gbé wọn sí ibi mímọ́ jùlọ. Gígùn gbogbo ìyẹ́ kerubu mejeeji jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ìyẹ́ kerubu kinni keji jẹ́ igbọnwọ marun-un (mita 2¼), ọ̀kan ninu àwọn ìyẹ́ kerubu kinni nà kan ògiri ilé náà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ìyẹ́ rẹ̀ keji tí òun náà jẹ́ igbọnwọ marun-un (mita 2¼), nà kan ìyẹ́ kerubu keji. Ekinni ninu àwọn ìyẹ́ kerubu keji náà jẹ́ igbọnwọ marun-un, ó nà kan ògiri ilé náà lẹ́gbẹ̀ẹ́ keji, ìyẹ́ rẹ̀ keji náà jẹ́ igbọnwọ marun-un, òun náà nà kan ìyẹ́ ti kerubu kinni. Àwọn kerubu yìí dúró, wọ́n kọjú sí gbọ̀ngàn ilé náà; gígùn gbogbo ìyẹ́ wọn jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). Ó fi aṣọ aláwọ̀ aró, ti elése àlùkò, ti àlàárì ati aṣọ ọ̀gbọ̀ onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe aṣọ ìbòjú fún ibi mímọ́ jùlọ, ó sì ya àwòrán kerubu sí i lára. Ó ṣe òpó meji sí iwájú ilé náà, ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀ ga ní igbọnwọ marundinlogoji (mita 15). Ọpọ́n orí ọ̀kọ̀ọ̀kan ga ní ìwọ̀n igbọnwọ marun-un (mita 2¼). Ó ṣe àwọn nǹkankan bí ẹ̀wọ̀n, ó fi wọ́n sórí àwọn òpó náà. Ó sì ṣe ọgọrun-un (100) èso pomegiranate, ó so wọ́n mọ́ àwọn ẹ̀wọ̀n náà. Ó gbé àwọn òpó náà kalẹ̀ níwájú tẹmpili, ọ̀kan ní ìhà àríwá, wọ́n ń pè é ní Jakini, ekeji ní ìhà gúsù, wọ́n ń pè é ní Boasi. Solomoni ọba ṣe pẹpẹ idẹ kan tí ó gùn ní ogún igbọnwọ (mita 9), ìbú rẹ̀ náà sì jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). Ó ga ní igbọnwọ mẹ́wàá (mita 4½). Ó ṣe agbada omi kan tí ó fẹ̀ ní igbọnwọ mẹ́wàá (mita 4½), ó sì ga ní igbọnwọ marun-un (mita 2¼). Àyíká etí rẹ̀ jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ (mita 13½). Gbogbo ẹ̀yìn agbada yìí ni ó ya àwòrán mààlúù sí ní ìlà meji meji yíká ìsàlẹ̀ etí rẹ̀. Agbada yìí wà lórí ère mààlúù mejila tí wọ́n kọjú síta: mẹta kọjú sí ìhà àríwá, mẹta kọjú sí ìwọ̀ oòrùn, mẹta kọjú sí ìhà gúsù, mẹta yòókù sì kọjú sí ìlà oòrùn. Agbada náà nípọn tó ìbú àtẹ́lẹwọ́, etí rẹ̀ dàbí etí ife omi ati bí òdòdó lílì. Agbada náà gbà tó ẹgbẹẹdogun ìwọ̀n bati omi. Ó ṣe abọ́ ńlá mẹ́wàá, ó gbé marun-un ka ẹ̀gbẹ́ gúsù, ó sì gbé marun-un yòókù ka ẹ̀gbẹ́ àríwá. Àwọn abọ́ wọnyi ni wọ́n fi ń bu omi láti fọ àwọn ohun tí wọn ń lò fún ẹbọ sísun. Omi inú agbada náà sì ni àwọn alufaa máa ń lò láti fi wẹ̀. Solomoni ṣe ọ̀pá fìtílà wúrà mẹ́wàá bí àpẹẹrẹ tí wọ́n fún un. Ó gbé wọn kalẹ̀ ninu tẹmpili: marun-un ní ìhà gúsù, marun-un yòókù ní ìhà àríwá. Ó ṣe tabili mẹ́wàá, ó gbé wọn kalẹ̀ ninu tẹmpili: marun-un ní ìhà gúsù, marun-un yòókù ní ìhà àríwá. Ó sì ṣe ọgọrun-un àwo kòtò wúrà. Ó kọ́ gbọ̀ngàn kan fún àwọn alufaa, ati òmíràn tí ó tóbi, ó ṣe ìlẹ̀kùn sí wọn, ó sì yọ́ idẹ bo àwọn ìlẹ̀kùn náà. Ó gbé agbada omi kalẹ̀ sí apá gúsù ìhà ìlà oòrùn igun ilé náà. Huramu mọ ìkòkò, ó rọ ọkọ́, ó sì ṣe àwọn àwo kòtò. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe parí iṣẹ́ tí ó ṣe sinu ilé Ọlọrun fún Solomoni ọba. Àwọn iṣẹ́ náà nìwọ̀nyí: Òpó meji, àwọn ọpọ́n meji tí wọ́n dàbí abọ́ tí wọ́n wà lórí àwọn òpó náà, nǹkankan tí ó dàbí ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi dárà sára àwọn ọpọ́n tí ó wà lórí òpó náà, àwọn irinwo òdòdó idẹ tí wọ́n fi ṣe ọnà ní ìlà meji meji yí ọpọ́n orí àwọn òpó náà ká. Ó ṣe àwọn abọ́ ńlá ati ìjókòó wọn. Ó ṣe agbada omi kan ati ère mààlúù mejila sí abẹ́ rẹ̀. Ó mọ àwọn ìkòkò, ó rọ ọkọ́ ati àmúga tí wọ́n fi ń mú ẹran, ati gbogbo ohun èlò wọn. Idẹ dídán ni Huramu fi ṣe gbogbo wọn fún Solomoni ọba, fún lílò ninu ilé OLUWA. Ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jọdani tí ó jẹ́ ilẹ̀ amọ̀, láàrin Sukotu ati Sereda ni ọba ti ṣe wọ́n. Àwọn nǹkan tí Solomoni ṣe pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí a kò fi mọ ìwọ̀n idẹ tí ó lò. Solomoni ṣe àwọn nǹkan wọnyi sí ilé Ọlọrun: pẹpẹ wúrà, tabili fún burẹdi ìfihàn. Àwọn ọ̀pá ati fìtílà tí wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe láti máa jò níwájú ibi mímọ́ jùlọ gẹ́gẹ́ bí a ti pa á láṣẹ. Ó fi wúrà tí ó dára jùlọ ṣe àwọn òdòdó, àwọn fìtílà ati àwọn ẹ̀mú. Ó fi ojúlówó wúrà ṣe ohun tí wọ́n fi ń tún òwú fìtílà ṣe ati àwọn àwo kòtò; àwọn àwo turari, ati àwọn àwo ìmúná. Wúrà ni wọ́n fi ṣe àwọn ìlẹ̀kùn ìta tẹmpili, ati ìlẹ̀kùn síbi mímọ́ jùlọ, ati ìlẹ̀kùn gbọ̀ngàn tẹmpili náà. Nígbà tí Solomoni ọba parí gbogbo iṣẹ́ ilé OLUWA, ó kó gbogbo nǹkan tí Dafidi baba rẹ̀ ti yà sí mímọ́ wá sinu ilé Ọlọrun: àwọn nǹkan bíi fadaka, wúrà, ati gbogbo ohun èlò, ó pa wọ́n mọ́ ninu àwọn ilé ìṣúra tí wọ́n wà níbẹ̀. Lẹ́yìn náà, Solomoni pe gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli jọ, àwọn olórí ẹ̀yà, ati àwọn baálé baálé ní ìdílé Israẹli ati ti Jerusalẹmu, láti gbé àpótí majẹmu OLUWA láti Sioni, ìlú Dafidi, wá sinu tẹmpili. Gbogbo wọn péjọ sọ́dọ̀ ọba ní àkókò àjọ̀dún, ní oṣù keje. Nígbà tí àwọn àgbààgbà péjọ tán, àwọn ọmọ Lefi gbé àpótí náà. Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi gbé àpótí náà wá pẹlu àgọ́ àjọ, ati gbogbo ohun èlò mímọ́ tí ó wà ninu àgọ́ àjọ náà. Solomoni ọba ati gbogbo ìjọ Israẹli dúró níwájú àpótí majẹmu, wọ́n ń fi ọpọlọpọ aguntan ati ọpọlọpọ mààlúù tí kò níye rúbọ. Àwọn alufaa gbé àpótí majẹmu OLUWA wá sí ààyè rẹ̀ ninu tẹmpili ní ibi mímọ́ jùlọ, wọ́n gbé e sí abẹ́ àwọn ìyẹ́ kerubu. Àwọn kerubu na àwọn ìyẹ́ wọn sórí ibi tí àpótí náà wà tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n bo àpótí náà ati àwọn òpó rẹ̀. Àwọn ọ̀pá náà gùn tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi lè rí orí wọn láti ibi mímọ́ jùlọ, ṣugbọn wọn kò lè rí wọn láti ìta. Wọ́n wà níbẹ̀ títí di òní olónìí. Ohun kan ṣoṣo tí ó wà ninu àpótí náà ni tabili meji tí Mose kó sibẹ ní òkè Horebu, níbi tí Ọlọrun ti bá àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Ijipti. Gbogbo àwọn alufaa jáde wá láti ibi mímọ́, (nítorí gbogbo àwọn alufaa tí wọ́n wà níbẹ̀ ti ya ara wọn sí mímọ́ láìbèèrè ìpín tí olukuluku wà. Gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n jẹ́ akọrin: Asafu, Hemani, Jedutuni, àwọn ọmọkunrin wọn ati àwọn ìbátan wọn dúró ní apá ìhà ìlà oòrùn pẹpẹ. Wọ́n wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, wọ́n ń fi ìlù, hapu ati dùùrù kọrin; pẹlu ọgọfa alufaa tí wọ́n ń fi fèrè kọrin, àwọn onífèrè ati àwọn akọrin pa ohùn pọ̀ wọ́n ń kọ orin ìyìn ati orin ọpẹ́ sí OLUWA). Wọ́n ń fi fèrè ati ìlù ati àwọn ohun èlò orin mìíràn kọrin ìyìn sí OLUWA pé: “OLUWA ṣeun, ìfẹ́ ńlá Rẹ̀ kò lópin.” Ìkùukùu kún inú tẹmpili OLUWA, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn alufaa kò fi lè ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn, nítorí ògo OLUWA tí ó kún ilé Ọlọrun. Solomoni ọba ní, “OLUWA, o ti sọ pé o óo máa gbé inú òkùnkùn biribiri. Ṣugbọn nisinsinyii, mo ti kọ́ ilé kan tí ó lógo fún ọ, ibi tí o óo máa gbé títí lae.” Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli wà níbẹ̀, ọba bá yíjú pada sí wọn, ó sì gbadura fún wọn. Lẹ́yìn náà, ó ní, “Ẹni ìyìn ni OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí ó mú ohun gbogbo tí ó wí fún Dafidi, baba mi, ṣẹ fúnrarẹ̀, nítorí ó wí pé, ‘Láti ìgbà tí mo ti mú àwọn eniyan jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, n kò tíì yan ìlú kankan ninu ẹ̀yà Israẹli láti kọ́ ilé sí fún ìjọ́sìn ní orúkọ mi, bẹ́ẹ̀ ni n kò yan ẹnìkan kan láti jẹ́ olórí àwọn eniyan mi. Ṣugbọn nisinsinyii, mo yan Jerusalẹmu fún ibi ìjọ́sìn ní orúkọ mi, mo sì ti yan Dafidi láti jẹ́ olórí Israẹli, eniyan mi.’ ” Ó wu Dafidi, baba mi, láti kọ́ ilé kan fún ìjọ́sìn ní orúkọ OLUWA Ọlọrun Israẹli. Ṣugbọn OLUWA sọ fún baba mi pé nǹkan dáradára ni pé ó wù ú lọ́kàn láti kọ́ ilé kan fún òun Ọlọrun, ṣugbọn kì í ṣe òun ni yóo kọ́ ilé náà, ọmọ bíbí inú rẹ̀ ni yóo kọ́ ilé fún òun. “Nisinsinyii OLUWA ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Mo ti wà ní ipò baba mi, mo ti gorí ìtẹ́ ọba Israẹli, bí OLUWA ti ṣèlérí, mo sì ti kọ́ tẹmpili fún OLUWA Ọlọrun Israẹli. Mo ti gbé àpótí ẹ̀rí sibẹ, inú rẹ̀ sì ni majẹmu tí OLUWA bá àwọn eniyan Israẹli dá wà.” Lẹ́yìn náà, Solomoni dúró níwájú pẹpẹ lójú gbogbo eniyan, ó gbé ọwọ́ mejeeji sókè, ó sì gbadura sí Ọlọrun. Solomoni ti ṣe pẹpẹ bàbà kan, ó gbé e sí àgbàlá ilé náà. Gígùn ati ìbú rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ marun-un (mita 2¼), gíga rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹta (1.3 mita). Solomoni gun orí pẹpẹ yìí, níbi tí gbogbo eniyan ti lè rí i. Ó kúnlẹ̀, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí Ọlọrun; ó bá gbadura pé, “OLUWA, Ọlọrun Israẹli, kò sí Ọlọrun tí ó dàbí rẹ ní ọ̀run tabi ní ayé, ìwọ tí ò ń pa majẹmu mọ́, tí o sì ń fi ìfẹ́ ńlá han àwọn iranṣẹ rẹ, tí wọn ń fi tọkàntọkàn tẹ̀lé ìlànà rẹ. O ti mú ìlérí rẹ ṣẹ fún baba mi, Dafidi, iranṣẹ rẹ. O fi ẹnu rẹ ṣèlérí, o sì ti fi ọwọ́ ara rẹ mú ìlérí náà ṣẹ lónìí. Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun Israẹli, jẹ́ kí ìlérí tí o ṣe fún Dafidi, baba mi ṣẹ, pé, ìran rẹ̀ ni yóo máa jọba ní Israẹli títí lae, bí wọn bá ń tẹ̀lé ìlànà rẹ, tí wọ́n sì ń pa òfin rẹ mọ́ gẹ́gẹ́ bí Dafidi ti ṣe. Nisinsinyii, jọ̀wọ́ Ọlọrun Israẹli, mú ọ̀rọ̀ rẹ tí o sọ fún Dafidi, iranṣẹ rẹ ṣẹ. “Ṣugbọn ṣé ìwọ Ọlọrun yóo máa bá eniyan gbé lórí ilẹ̀ ayé? Bí ọ̀run ti tóbi tó, kò gbà ọ́, mélòó mélòó ni ilé tí mo kọ́ yìí? Sibẹsibẹ, jọ̀wọ́ fetí sí adura ati ẹ̀bẹ̀ èmi iranṣẹ rẹ. OLUWA Ọlọrun mi, gbọ́ igbe èmi iranṣẹ rẹ, ati adura tí mò ń gbà níwájú rẹ. Máa bojútó ilé yìí tọ̀sán-tòru. O ti sọ pé ibẹ̀ ni àwọn eniyan yóo ti máa jọ́sìn ní orúkọ rẹ. Jọ̀wọ́ máa gbọ́ adura tí èmi iranṣẹ rẹ bá gbà nígbà tí mo bá kọjú sí ilé yìí. Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ èmi iranṣẹ rẹ, ati ti Israẹli, eniyan rẹ, nígbà tí wọ́n bá kọjú sí ibí yìí láti gbadura. Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa láti ibùgbé rẹ ní ọ̀run, kí o sì dáríjì wá. “Bí ẹnìkan bá ṣẹ aládùúgbò rẹ̀, tí a sì mú un wá kí ó wá búra níwájú pẹpẹ rẹ ninu ilé yìí, OLUWA, gbọ́ láti ọ̀run, kí o ṣe ìdájọ́ àwọn iranṣẹ rẹ. Jẹ ẹni tí ó bá ṣẹ̀ níyà bí ó ti tọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí o dá ẹni tí kò ṣẹ̀ láre gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ̀. “Nígbà tí àwọn ọ̀tá bá ṣẹgun àwọn eniyan rẹ lójú ogun nítorí pé wọ́n ti ṣẹ̀ ọ́, ṣugbọn bí wọ́n bá ronupiwada, tí wọ́n ranti orúkọ rẹ, tí wọ́n bá gbadura, tí wọ́n sì bẹ̀ ọ́ ninu ilé yìí, jọ̀wọ́ gbọ́ láti ọ̀run, kí o dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, jì wọ́n, kí o sì mú wọn pada sórí ilẹ̀ tí o ti fún àwọn ati àwọn baba wọn. “Nígbà tí òjò bá kọ̀ tí kò rọ̀, nítorí pé àwọn eniyan rẹ ṣẹ̀, bí wọ́n bá kọjú sí ilé yìí, tí wọ́n sì gbadura, tí wọ́n jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nítorí pé o ti jẹ wọ́n níyà, jọ̀wọ́, gbọ́ láti ọ̀run, kí o sì dáríjì àwọn eniyan Israẹli, àwọn iranṣẹ rẹ. Tọ́ wọn sí ọ̀nà tí wọn yóo máa tọ̀, kí o sì jẹ́ kí òjò rọ̀ sí ilẹ̀ tí o fún àwọn eniyan rẹ gẹ́gẹ́ bí ìní wọn. “Nígbàkúùgbà tí ìyàn bá mú ní ilẹ̀ yìí, tabi tí àjàkálẹ̀ àrùn bá bẹ́ sílẹ̀, tabi ọ̀gbẹlẹ̀, tabi ìrẹ̀dànù ohun ọ̀gbìn, tabi eṣú, tabi kòkòrò tíí máa jẹ ohun ọ̀gbìn; tabi tí àwọn ọ̀tá bá gbógun ti èyíkéyìí ninu àwọn ìlú wọn, irú ìyọnu tabi àìsàn yòówù tí ó lè jẹ́, gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan, tabi ti gbogbo Israẹli, eniyan rẹ, lẹ́yìn tí olukuluku ti mọ ìṣòro ati ìbànújẹ́ rẹ̀, bí wọ́n bá gbé ọwọ́ adura wọn sókè sí ìhà ilé yìí, jọ̀wọ́, gbọ́ láti ilé rẹ ní ọ̀run, dáríjì wọ́n, kí o sì ṣe ẹ̀tọ́ fún olukuluku gẹ́gẹ́ bí ìwà rẹ̀, nítorí ìwọ nìkan ni o mọ ọkàn ọmọ eniyan. Kí àwọn eniyan rẹ lè máa bẹ̀rù rẹ, kí wọ́n sì máa rìn ní ọ̀nà rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn lórí ilẹ̀ tí o fún àwọn baba wa. “Bákan náà, nígbà tí àwọn àjèjì, tí kì í ṣe ara àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, bá ti ọ̀nà jíjìn wá, láti gbadura sí ìhà ilé yìí, nítorí orúkọ ńlá rẹ, ati iṣẹ́ ńlá, ati agbára rẹ, gbọ́ láti ibùgbé rẹ lọ́run; kí o sì ṣe gbogbo ohun tí àjèjì náà bá ń tọrọ lọ́dọ̀ rẹ, kí gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà láyé lè mọ orúkọ rẹ, kí wọ́n sì máa bẹ̀rù rẹ, bí àwọn eniyan rẹ tí ń ṣe, kí wọ́n lè mọ̀ pé ilé ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ, ni ilé tí mo kọ́ yìí. “Nígbà tí àwọn eniyan rẹ bá lọ sójú ogun, níbikíbi tí o bá rán wọn, láti lọ bá àwọn ọ̀tá wọn jà, tí wọ́n bá kọjú sí ìhà ìlú tí o ti yàn yìí ati sí ìhà ilé tí mo kọ́ fún ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ yìí, gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ wọn láti ọ̀run, kí o sì jà fún wọn. “Bí wọ́n bá ṣẹ̀ ọ́ (nítorí pé kò sí ẹni tí kì í ṣẹ̀), tí inú bá bí ọ sí wọn, tí o sì mú kí àwọn ọ̀tá wọn ṣẹgun wọn, tí wọ́n sì kó wọn lẹ́rú lọ sí ọ̀nà jíjìn tabi nítòsí, sibẹ, tí wọ́n bá ranti, tí wọ́n sì ronupiwada ní ilẹ̀ tí wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ, tí wọ́n bá bẹ̀bẹ̀ tí wọ́n sọ pé, ‘àwọn ti ṣẹ̀, àwọn ti hu ìwà tí kò tọ́, àwọn sì ti ṣe burúkú,’ tí wọ́n bá ronupiwada tọkàntọkàn ninu ìgbèkùn níbi tí a kó wọn lẹ́rú lọ, tí wọ́n gbadura sí ìhà ilẹ̀ tí o fún àwọn baba wọn, ati sí ìlú tí o ti yàn, ati sí ilé tí mo kọ́ fún ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ, gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ wọn láti ibùgbé rẹ lọ́run, jà fún àwọn eniyan rẹ, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n bá ṣẹ̀ ọ́ jì wọ́n. “Nisinsinyii, Ọlọrun mi, bojúwò wá kí o sì tẹ́tí sí adura tí wọ́n bá gbà níhìn-ín. Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun, dìde, lọ sí ibùjókòó rẹ, ìwọ ati àpótí ẹ̀rí agbára rẹ. Gbé ìgbàlà rẹ wọ àwọn alufaa rẹ bí ẹ̀wù, kí o sì jẹ́ kí àwọn eniyan mímọ́ rẹ yọ̀ ninu ire rẹ. Áà! OLUWA Ọlọrun, má ṣe kọ ẹni tí a fi òróró yàn, ranti ìfẹ́ rẹ tí kìí yẹ̀ sí Dafidi, iranṣẹ rẹ.” Nígbà tí Solomoni parí adura rẹ̀, iná kan ṣẹ́ láti ọ̀run, ó jó gbogbo ẹbọ sísun ati ọrẹ, ògo OLUWA sì kún inú tẹmpili. Àwọn alufaa kò sì lè wọ inú tẹmpili lọ mọ́ nítorí ògo OLUWA ti kún ibẹ̀. Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli rí i bí iná ati ògo OLUWA ti sọ̀kalẹ̀ sórí tẹmpili, wọ́n dojúbolẹ̀, wọ́n sin Ọlọrun, wọ́n fi ọpẹ́ fún un, “Nítorí pé ó ṣeun, nítorí pé àánú rẹ̀ wà títí lae.” Lẹ́yìn náà, ọba ati gbogbo àwọn eniyan rúbọ sí OLUWA. Solomoni ọba fi ẹgbaa mọkanla (22,000) mààlúù ati ọ̀kẹ́ mẹfa (120,000) aguntan rúbọ. Bẹ́ẹ̀ ni ọba ati gbogbo àwọn eniyan náà ṣe ya ilé Ọlọrun sí mímọ́. Àwọn alufaa dúró ní ipò wọn, àwọn ọmọ Lefi náà dúró láti kọrin sí OLUWA pẹlu ohun èlò orin tí Dafidi ṣe ati ìlànà tí ó fi lélẹ̀ láti máa fi kọrin ọpẹ́ sí OLUWA pé, “Ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀ wà títí lae;” ní gbogbo ìgbà tí Dafidi bá lò wọ́n láti kọrin ìyìn. Àwọn alufaa yóo máa fọn fèrè gbogbo eniyan yóo sì dìde dúró. Solomoni ya gbọ̀ngàn ààrin tí ó wà níwájú ilé OLUWA sí mímọ́, nítorí pé ibẹ̀ ni ó ti rú ẹbọ sísun tí ó sì sun ọ̀rá ẹran fún ẹbọ alaafia, nítorí pé pẹpẹ bàbà tí ó ṣe kò lè gba gbogbo ẹbọ sísun, ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ọ̀rá. Solomoni ṣe àjọyọ̀ yìí fún ọjọ́ meje gbáko, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ Israẹli wà pẹlu rẹ̀, eniyan pọ̀ lọ bí eṣú, láti ẹnu bodè Hamati títí dé odò Ijipti. Wọ́n fi ọjọ́ meje ṣe ìyàsímímọ́ pẹpẹ, wọ́n sì fi ọjọ́ meje ṣe àjọyọ̀. Ní ọjọ́ kẹjọ wọ́n pe àpéjọ mímọ́. Ní ọjọ́ kẹtalelogun oṣù keje, Solomoni ní kí àwọn eniyan máa pada lọ sílé wọn. Inú wọn dùn nítorí ohun rere tí OLUWA ṣe fún Dafidi, ati Solomoni ati gbogbo Israẹli. Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ṣe parí ilé OLUWA ati ààfin rẹ̀. Gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn láti ṣe sí ilé OLUWA ati sí ilé ti ara rẹ̀, ni ó ṣe ní àṣeyọrí. Lẹ́yìn náà, OLUWA fara han Solomoni lóru, ó ní, “Mo ti gbọ́ adura rẹ, mo sì ti yan ibí yìí ní ilé ìrúbọ fúnra mi. Nígbà tí mo bá sé ojú ọ̀run, tí òjò kò bá rọ̀, tabi tí mo pàṣẹ fún eṣú láti ba oko jẹ́, tabi tí mo rán àjàkálẹ̀ àrùn sí ààrin àwọn eniyan mi, bí àwọn eniyan mi, tí à ń fi orúkọ mi pè, bá rẹ ara wọn sílẹ̀, tí wọ́n bá gbadura, tí wọ́n sì wá ojurere mi, tí wọ́n bá yipada kúrò ní ọ̀nà burúkú wọnyi; n óo gbọ́ láti ọ̀run, n óo dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, n óo sì wo ilẹ̀ wọn sàn. Nisinsinyii, n óo fojú sílẹ̀, etí mi yóo sì ṣí sí adura tí wọ́n bá gbà níbí yìí. Mo ti yan ibí yìí, mo sì ti yà á sí mímọ́, kí á lè máa jọ́sìn ní orúkọ mi níbẹ̀ títí lae. Ojú ati ọkàn mi yóo wà níbẹ̀ nígbà gbogbo. Ṣugbọn, bí ìwọ bá tẹ̀lé ìlànà mi gẹ́gẹ́ bí Dafidi baba rẹ ti ṣe, tí o pa gbogbo òfin mi mọ́, tí o tẹ̀lé ìlànà ati àṣẹ mi, n óo fi ìdí ìjọba rẹ múlẹ̀, bí mo ti bá Dafidi, baba rẹ, dá majẹmu pé, ìran rẹ̀ ni yóo máa jọba lórí Israẹli. Ṣugbọn tí o bá yipada kúrò lọ́dọ̀ mi, tí o kọ àṣẹ mi ati òfin tí mo ṣe fún ọ sílẹ̀, tí o sì ń lọ bọ oriṣa, tí ò ń foríbalẹ̀ fún wọn, n óo fà yín tu kúrò lórí ilẹ̀ tí mo fun yín bí ẹni fa igi tu. N óo sì kọ tẹmpili yìí, tí mo ti yà sí mímọ́ fún ìjọ́sìn ní orúkọ mi sílẹ̀, nítorí pé yóo di ohun ẹ̀gàn ati àmúpòwe láàrin gbogbo eniyan. “Tẹmpili yìí gbayì gidigidi nisinsinyii, ṣugbọn nígbà náà, àwọn ẹni tó bá ń rékọjá lọ yóo máa sọ tìyanu-tìyanu pé, ‘Kí ló dé tí Ọlọrun fi ṣe báyìí sí ilẹ̀ yìí ati sí tẹmpili yìí?’ Àwọn eniyan yóo dáhùn pé, ‘Nítorí pé wọ́n kọ OLUWA, Ọlọrun àwọn baba wọn sílẹ̀, tí ó mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, wọ́n ń lọ bọ oriṣa, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún wọn. Ìdí nìyí tí ibi yìí fi bá wọn.’ ” Ó gba Solomoni ní ogún ọdún láti kọ́ tẹmpili OLUWA ati ààfin tirẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó tún àwọn ìlú tí Huramu ọba, fún un kọ́, ó sì fi àwọn ọmọ Israẹli sibẹ. Ó lọ gbógun ti ìlú Hamati ati Soba, ó sì ṣẹgun wọn. Ó kọ́ ìlú Tadimori ní aṣálẹ̀, ati gbogbo ìlú tí wọn ń kó ìṣúra jọ sí ní Hamati. Ó kọ́ ìlú Beti Horoni ti òkè ati Beti Horoni ti ìsàlẹ̀. Wọ́n jẹ́ ìlú olódi, wọ́n ní ìlẹ̀kùn ati ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn, bẹ́ẹ̀ sì ni ìlú Baalati ati gbogbo ìlú tí wọn ń kó ìṣúra pamọ́ sí, ati àwọn ìlú tí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ wà, ati ìlú fún àwọn ẹlẹ́ṣin, ati gbogbo ohun tí ó pinnu lọ́kàn rẹ̀ láti kọ́ ní Jerusalẹmu, ati ní Lẹbanoni, ati ní gbogbo ibi tí ìjọba rẹ̀ dé. Gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n kù ní ilẹ̀ náà lára àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Amori, àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi ati àwọn ará Jebusi, tí wọn kì í ṣe ọmọ Israẹli, gbogbo ìran àwọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà, tí àwọn ọmọ Israẹli kò parun, ni Solomoni ń fi tipátipá kó ṣiṣẹ́ títí di òní olónìí. Ṣugbọn kò fi ipá kó àwọn ọmọ Israẹli ṣiṣẹ́ bí ẹrú, ṣugbọn ó ń lò wọ́n bíi jagunjagun, òṣìṣẹ́ ìjọba, balogun kẹ̀kẹ́ ogun, ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀. Àwọn olórí lára àwọn òṣìṣẹ́ Solomoni jẹ́ igba ati aadọta (250), àwọn ni wọ́n ń ṣe àkóso àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́. Solomoni mú iyawo rẹ̀, ọmọ Farao kúrò ní ìlú Dafidi, lọ sí ibi tí ó kọ́ fún un. Ó ní, “Iyawo mi kò gbọdọ̀ máa gbé ààfin Dafidi, ọba Israẹli; nítorí pé ibikíbi tí àpótí OLUWA bá ti wọ̀, ó ti di ibi mímọ́.” Solomoni rú ẹbọ sísun sí OLUWA lórí pẹpẹ OLUWA tí ó kọ́ siwaju yàrá àbáwọlé ní tẹmpili. Ó ń rú ẹbọ sísun gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Mose ti fi lélẹ̀, lojoojumọ, ati ní gbogbo ọjọ́ ìsinmi, ati ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù tuntun ati àwọn àjọ̀dún mẹta pataki tí wọ́n gbọdọ̀ ṣe lọdọọdun: àjọ àìwúkàrà, àjọ ìkórè ati àjọ ìpàgọ́. Gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Dafidi fi lélẹ̀, Solomoni pín àwọn alufaa sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn, ó sì pín àwọn ọmọ Lefi sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí láti máa kọ orin ìyìn ati láti máa ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn alufaa ninu iṣẹ́ wọn ojoojumọ. Ó yan àwọn aṣọ́nà sí oríṣìíríṣìí ẹnu ọ̀nà gẹ́gẹ́ bí Dafidi eniyan Ọlọrun ti pa á láṣẹ. Wọn kò sì yapa kúrò ninu ìlànà tí Dafidi fi lélẹ̀ fún àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi nípa àwọn ohun tí wọ́n gbọdọ̀ máa ṣe, ati nípa ilé ìṣúra. Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ṣe ṣe gbogbo iṣẹ́ tí ó ṣe láti ìgbà tí ó ti fi ìpìlẹ̀ ilé OLUWA lélẹ̀ títí di ìgbà tí ó parí iṣẹ́ náà patapata. Solomoni lọ sí Esiongeberi ati Elati ní etí òkun ní ilẹ̀ Edomu. Huramu fi àwọn ọkọ̀ ojú omi ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí wọ́n mọ̀ nípa iṣẹ́ ọkọ̀ ojú omi ranṣẹ, wọ́n lọ sí ilẹ̀ Ofiri pẹlu àwọn iranṣẹ Solomoni, wọ́n sì kó ojilenirinwo ati mẹ́wàá (450) ìwọ̀n talẹnti wúrà wá fún Solomoni ọba. Nígbà tí ọbabinrin ìlú Ṣeba gbọ́ nípa òkìkí Solomoni, ó wá sí Jerusalẹmu láti wá dán an wò pẹlu àwọn ìbéèrè tó le. Ó wá ninu ọlá ńlá rẹ̀. Ọ̀pọ̀ eniyan ni wọ́n tẹ̀lé e lẹ́yìn, pẹlu àwọn ràkúnmí tí wọ́n ru oríṣìírìṣìí turari olóòórùn dídùn, ati ọpọlọpọ wúrà ati òkúta olówó iyebíye. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Solomoni, ó sọ gbogbo ohun tí ó wà lọ́kàn rẹ̀ fún un. Solomoni dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀. Kò sí ẹyọ kan tí ó rú Solomoni lójú, tí kò dáhùn pẹlu àlàyé. Nígbà tí ọbabinrin Ṣeba rí i bí ọgbọ́n Solomoni ti jinlẹ̀ tó, ati ààfin tí ó kọ́, oúnjẹ tí ó wà lórí tabili rẹ̀ ati bí àwọn ìjòyè rẹ̀ ti jókòó, àwọn iranṣẹ rẹ̀, ìwọṣọ ati ìṣesí wọn, àwọn agbọ́tí rẹ̀ ati ìwọṣọ wọn, ati ẹbọ sísun tí ó ń rú ní ilé OLUWA, ẹnu yà á lọpọlọpọ. Ó sọ fún Solomoni ọba pé, “Kò sí irọ́ ninu gbogbo ohun tí mo ti gbọ́ nípa rẹ ati nípa ọgbọ́n rẹ. N kò gba ohun tí wọ́n sọ fún mi gbọ́ títí tí mo fi dé ìhín, tí èmi gan-an sì fi ojú ara mi rí i. Ohun tí wọ́n sọ fún mi kò tó ìdajì ọgbọ́n rẹ, ohun tí mo rí yìí pọ̀ ju ohun tí wọ́n sọ fún mi lọ. Àwọn iyawo rẹ ṣoríire. Àwọn òṣìṣẹ́ rẹ tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ nígbà gbogbo tí wọn ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n rẹ náà ṣoríire. Ògo ni fún OLUWA Ọlọrun rẹ, tí inú rẹ̀ dùn sí ọ, tí ó gbé ọ gorí oyè láti jọba ní orúkọ rẹ̀. Ó ní ìfẹ́ sí Israẹli, ó fẹ́ fi ìdí wọn múlẹ̀ títí lae; nítorí náà, ó fi ọ́ jọba lórí wọn, láti máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́ ati òdodo.” Ó fún ọba ní àwọn ẹ̀bùn wọnyi tí ó mú wá: ọgọfa (120) ìwọ̀n talẹnti wúrà, ọpọlọpọ turari olóòórùn dídùn ati ohun ọ̀ṣọ́ òkúta olówó iyebíye. Kò tún sí irú turari tí ọbabinrin yìí mú wá fún Solomoni ọba mọ́. Àwọn iranṣẹ Huramu ati àwọn iranṣẹ Solomoni tí wọ́n mú wúrà wá láti Ofiri, tún mú igi aligumu ati àwọn òkúta olówó iyebíye wá pẹlu. Igi aligumu yìí ni ọba fi ṣe àtẹ̀gùn láti máa gòkè ati láti máa sọ̀kalẹ̀ ninu tẹmpili OLUWA ati ninu ààfin ọba. Ó tún fi ṣe dùùrù ati hapu fún àwọn akọrin. Kò sí irú wọn rí ní gbogbo ilẹ̀ Juda. Solomoni ọba fún ọbabinrin náà ní gbogbo ohun tí ọkàn rẹ̀ ń fẹ́. Ẹ̀bùn tí ó fún un ju èyí tí òun alára mú wá lọ. Lẹ́yìn náà ọbabinrin náà pada lọ sí ìlú rẹ̀. Ìwọ̀n wúrà tí Solomoni ń rí ní ọdọọdún jẹ́ ọtalelẹgbẹta ó lé mẹfa (666) talẹnti (kilogiramu 23,000), láìka èyí tí àwọn oníṣòwò ati àwọn ọlọ́jà ń mú wá. Àwọn ọba Arabia ati àwọn gomina àwọn agbègbè ìjọba rẹ̀ náà a máa mú wúrà ati fadaka wá fún un. Solomoni fi wúrà tí a fi òòlù lù ṣe igba (200) apata ńláńlá. Ìwọ̀n wúrà tí ó lò fún ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹgbẹta (600) ṣekeli. Ó tún fi wúrà tí a fi òòlù lù ṣe ọọdunrun (300) apata kéékèèké. Ìwọ̀n wúrà tí ó lò fún ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọọdunrun (300) ṣekeli. Ọba kó wọn sí ààfin Igbó Lẹbanoni. Ọba fi eyín erin ṣe ìtẹ́ ńlá kan, ó sì yọ́ ojúlówó wúrà bò ó. Ìtẹ́ náà ní àtẹ̀gùn kan tí ó ní ìṣísẹ̀ mẹfa ati àpótí ìtìsẹ̀ kan tí a fi wúrà ṣe, tí a kàn mọ́ ìtẹ́. Igbọwọle wà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ìtẹ́ náà, tí ère kinniun meji wà ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ wọn. Wọ́n ṣe ère kinniun mejila sí ẹ̀gbẹ́ àtẹ̀gùn náà, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji ìṣísẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Kò sí irú rẹ̀ rí ní ìjọba kankan. Wúrà ni wọ́n fi ṣe gbogbo ife Solomoni, ati gbogbo ohun èlò tí ó wà ní ilé Igbó Lẹbanoni. Fadaka kò jámọ́ nǹkankan ní àkókò ìjọba Solomoni. Nítorí pé, ọba ní àwọn ọkọ̀ ojú omi tí àwọn iranṣẹ Huramu máa ń gbé lọ sí Taṣiṣi. Ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún mẹta ni àwọn ọkọ̀ náà máa ń dé; wọn á máa kó wúrà, fadaka, eyín erin, ati oríṣìíríṣìí àwọn ọ̀bọ ati ẹyẹ ọ̀kín wá sílé. Solomoni ọba ní ọrọ̀ ati ọgbọ́n ju gbogbo àwọn ọba yòókù lọ lórí ilẹ̀ ayé. Gbogbo wọn ni wọ́n ń wá láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tí Ọlọrun fún un. Fún ọpọlọpọ ọdún ni ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn máa ń mú ẹ̀bùn wá fún un lọdọọdun, àwọn ẹ̀bùn bíi: ohun èlò fadaka, ati ti wúrà, aṣọ, ohun ìjà ogun, turari, ẹṣin, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Solomoni ọba ní ẹgbaaji (4,000) ilé fún ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun, ó ní ẹgbaafa (12,000) ẹlẹ́ṣin. Ó kó àwọn kan sí àwọn ìlú tí ó kó kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ sí, ó kó ìyókù sí Jerusalẹmu, níbi tí ọba ń gbé. Solomoni jọba lórí àwọn ọba gbogbo, láti odò Yufurate títí dé ilẹ̀ àwọn ará Filistia ati títí dé ààlà Ijipti. Ní àkókò tirẹ̀, ó mú kí fadaka pọ̀ bí òkúta ní Jerusalẹmu, igi kedari sì pọ̀ bíi igi sikamore tí ó wà ní ẹsẹ̀ òkè Juda. A máa ra ẹṣin wá láti Ijipti ati láti gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù. Gbogbo ìtàn ìjọba Solomoni, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, wà ninu ìwé ìtàn wolii Natani, ati ninu ìwé àsọtẹ́lẹ̀ Ahija ará Ṣilo, ati ninu ìwé ìran tí Ido rí nípa Jeroboamu ọba Israẹli, ọmọ Nebati. Solomoni jọba ní Jerusalẹmu lórí gbogbo Israẹli fún ogoji ọdún. Ó kú, a sì sin ín sí ìlú Dafidi, baba rẹ̀. Rehoboamu, ọmọ rẹ̀, ni ó jọba lẹ́yìn rẹ̀. Rehoboamu lọ sí Ṣekemu, nítorí pé gbogbo Israẹli ti péjọ sibẹ láti fi jọba. Nígbà tí Jeroboamu, ọmọ Nebati, gbọ́, ó pada wá láti Ijipti, níbi tí ó ti sá lọ fún Solomoni. Àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n ranṣẹ sí i, òun ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli lọ sọ́dọ̀ Rehoboamu, wọ́n wí fún un pé, “Àjàgà tí baba rẹ gbé bọ̀ wá lọ́rùn wúwo, ṣugbọn nisinsinyii, dín wahala tí baba rẹ fi wá ṣe kù, kí o sì sọ àjàgà wa di fúfúyẹ́, a óo sì máa sìn ọ́.” Rehoboamu bá dáhùn pé, “Ẹ pada wá gbọ́ èsì lẹ́yìn ọjọ́ mẹta.” Àwọn eniyan náà bá lọ. Rehoboamu bá lọ jíròrò pẹlu àwọn àgbààgbà Israẹli tí wọ́n bá baba rẹ̀ ṣiṣẹ́ nígbà ayé rẹ̀, ó ní, “Ẹ fún mi ní ìmọ̀ràn, irú èsì wo ni ó yẹ kí n fún àwọn eniyan wọnyi?” Wọ́n gbà á ní ìmọ̀ràn pé, “Bí o bá ṣe dáradára sí àwọn eniyan wọnyi, tí o bá ṣe ohun tí ó tẹ́ wọn lọ́rùn, tí o sì sọ̀rọ̀ dáradára fún wọn, wọn yóo máa sìn ọ́ títí lae.” Ṣugbọn Rehoboamu kọ ìmọ̀ràn àwọn àgbà. Ó lọ jíròrò pẹlu àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ dàgbà pọ̀, tí wọn ń bá a ṣiṣẹ́, ó bi wọ́n pé, “Kí ni èsì tí ó yẹ kí n fún àwọn tí wọ́n sọ fún mi pé kí n sọ àjàgà tí baba mi gbé bọ àwọn lọ́rùn di fúfúyẹ́?” Àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ sọ fún un pé, “Lọ sọ fún wọn pé, ‘Ìka ọwọ́ mi tí ó kéré jù yóo tóbi ju ẹ̀gbẹ́ baba mi lọ. Àjàgà wúwo ni baba mi gbé bọ̀ yín lọ́rùn, ṣugbọn tèmi yóo tún wúwo ju ti baba mi lọ. Pàṣán ni baba mi fi nà yín, ṣugbọn àkeekèé ni èmi óo fi ta yín.’ ” Ní ọjọ́ kẹta, Jeroboamu pẹlu àwọn ọmọ Israẹli bá pada wá sọ́dọ̀ Rehoboamu, gẹ́gẹ́ bí àdéhùn wọn. Ọba kọ ìmọ̀ràn àwọn àgbà, ó gbójú mọ́ wọn, ó sọ̀rọ̀ sí wọn gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn tí àwọn ọ̀dọ́ fún un, ó ní, “Àjàgà wúwo ni baba mi gbé bọ̀ yín lọ́rùn, ṣugbọn èmi óo tún fi kún àjàgà náà. Pàṣán ni baba mi fi nà yín, ṣugbọn àkeekèé ni èmi óo fi máa ta yín.” Ọba kò gbọ́ ti àwọn eniyan náà, nítorí pé ọwọ́ Ọlọrun ni àyípadà yìí ti wá, kí ó lè mú ohun tí ó ní kí wolii Ahija, ará Ṣilo, sọ fún Jeroboamu, ọmọ Nebati, ṣẹ. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli rí i pé Rehoboamu kò gbọ́ tiwọn, wọ́n dáhùn pé, “Kí ló kàn wá pẹlu ilé Dafidi? Kí ló pa wá pọ̀ pẹlu ọmọ Jese? Ẹ pada sinu àgọ́ yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli Dafidi, fọwọ́ mú ilé rẹ.” Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá pada lọ sí ilé wọn, ṣugbọn Rehoboamu jọba lórí àwọn ọmọ Israẹli tí wọn ń gbé Juda. Ọba rán Hadoramu tí ó jẹ́ olórí àwọn akóniṣiṣẹ́ sí àwọn ọmọ Israẹli, ṣugbọn wọ́n sọ ọ́ lókùúta pa. Rehoboamu ọba bá yára bọ́ sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó sá àsálà lọ sí Jerusalẹmu. Láti ìgbà náà lọ ni àwọn ọmọ Israẹli ti ń bá ilé Dafidi ṣọ̀tẹ̀ títí di òní olónìí. Nígbà tí Rehoboamu dé Jerusalẹmu, ó kó ọ̀kẹ́ mẹsan-an (180,000) àwọn akọni ọmọ ogun jọ láti inú ẹ̀yà Juda ati Bẹnjamini, láti bá àwọn ọmọ Israẹli jagun, kí ó lè fi ipá gba ìjọba rẹ̀ pada. Ṣugbọn OLUWA sọ fún wolii Ṣemaaya, eniyan Ọlọrun pé, “Sọ fún Rehoboamu ọmọ Solomoni, ọba Juda, ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọn ń gbé Juda ati Bẹnjamini pé, OLUWA ní, ‘Ẹ kò gbọdọ̀ lọ bá àwọn arakunrin yín jà. Kí olukuluku yín pada sí ilé rẹ̀ nítorí èmi ni mo jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí ó ṣẹlẹ̀.’ ” Wọ́n gbọ́ràn sí OLUWA lẹ́nu, wọ́n pada, wọn kò sì lọ bá Jeroboamu jagun mọ́. Rehoboamu ń gbé Jerusalẹmu, ó kọ́ àwọn ìlú ààbò wọnyi sí Juda: Bẹtilẹhẹmu, Etamu, ati Tekoa; Betisuri, Soko, ati Adulamu; Gati, Mareṣa, ati Sifi; Adoraimu, Lakiṣi, ati Aseka; Sora, Aijaloni ati Heburoni. Àwọn ni ìlú olódi ní Juda ati Bẹnjamini. Ó tún àwọn ìlú olódi ṣe, wọ́n lágbára, níbẹ̀ ni ó fi àwọn olórí ogun sí, ó sì kó ọpọlọpọ oúnjẹ, epo ati ọtí waini pamọ́ sibẹ. Ó kó ọ̀kọ̀ ati apata sinu gbogbo wọn, ó sì fi agbára kún agbára wọn. Bẹ́ẹ̀ ló ṣe fi ọwọ́ mú Juda ati Bẹnjamini. Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli sì fara mọ́ Rehoboamu. Gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí wọ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Àwọn ọmọ Lefi fi ilẹ̀ wọn sílẹ̀ ati ẹran ọ̀sìn wọn ati gbogbo ohun ìní wọn, wọ́n kó wá sí Juda, ati Jerusalẹmu; nítorí pé Jeroboamu ati àwọn ọmọ rẹ̀ lé wọn jáde, wọn kò jẹ́ kí wọ́n ṣe iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí alufaa Ọlọrun. Ó yan àwọn alufaa ti ara rẹ̀ fún ibi ìrúbọ ati fún ilé ère ewúrẹ́ ati ti ọmọ aguntan tí ó gbé kalẹ̀. Gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ sin Ọlọrun Israẹli tọkàntọkàn láti inú olukuluku ẹ̀yà Israẹli, tẹ̀lé àwọn alufaa wá sí Jerusalẹmu láti ṣe ìrúbọ sí OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn. Wọ́n sọ ìjọba Juda di alágbára, wọ́n sì ṣe alátìlẹ́yìn fún Rehoboamu ọmọ Solomoni fún ọdún mẹta; wọ́n ń rìn ní ìlànà Dafidi ati ti Solomoni ní gbogbo ìgbà náà. Rehoboamu fẹ́ Mahalati, ọmọ Jerimotu, ọmọ Dafidi, ìyá rẹ̀ ni Abihaili, ọmọ Eliabu, ọmọ Jese. Iyawo Rehoboamu yìí bí ọmọkunrin mẹta fún un; wọ́n ń jẹ́: Jeuṣi, Ṣemaraya ati Sahamu. Lẹ́yìn náà, ó tún fẹ́ Maaka, ọmọ Absalomu; òun bí ọmọkunrin mẹrin fún un; wọ́n ń jẹ́ Abija, Atai, Sisa ati Ṣelomiti. Maaka, ọmọ Absalomu ni Rehoboamu fẹ́ràn jùlọ ninu àwọn iyawo rẹ̀. Àwọn mejidinlogun ni ó gbé ní iyawo, o sì ní ọgọta obinrin mìíràn. Ó bí ọmọkunrin mejidinlọgbọn ati ọgọta ọmọbinrin. Ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ tí ń jẹ́ Abija ju gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù lọ. Ó yàn án láti jẹ́ ọba lẹ́yìn tí òun bá kú. Ó dọ́gbọ́n fi àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe olórí káàkiri, ó pín wọn káàkiri jákèjádò ilẹ̀ Juda ati Bẹnjamini ní àwọn ìlú alágbára. Ó fún wọn ní ohun tí wọ́n ṣe aláìní. Ó sì fẹ́ iyawo fún gbogbo wọn. Láìpẹ́, lẹ́yìn tí Rehoboamu fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ tí ó di alágbára, òun ati àwọn eniyan rẹ̀ kọ òfin OLUWA sílẹ̀. Nígbà tí ó di ọdún karun-un ìjọba rẹ̀, Ọlọrun fi ìyà jẹ ẹ́ nítorí aiṣootọ rẹ̀. Ṣiṣaki ọba Ijipti gbógun ti Jerusalẹmu pẹlu ẹgbẹfa (1,200) kẹ̀kẹ́ ogun, ati ọ̀kẹ́ mẹta (60,000) ẹlẹ́ṣin, ati ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ọmọ ogun tí wọ́n tẹ̀lé e láti Ijipti. Àwọn ará Libia, àwọn ará Sukiimu, ati àwọn ará Etiopia wà ninu àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ó gba gbogbo ìlú olódi Juda títí ó fi dé Jerusalẹmu. Lẹ́yìn náà, wolii Ṣemaaya lọ bá Rehoboamu ati gbogbo àwọn olóyè Juda, tí wọ́n ti péjọ sí Jerusalẹmu lórí ọ̀rọ̀ Ṣiṣaki ọba Ijipti. Ó sọ fún wọn pé, “OLUWA ní ẹ ti kọ òun sílẹ̀, nítorí náà ni òun ṣe fi yín lé Ṣiṣaki lọ́wọ́.” Àwọn ìjòyè ní Israẹli ati Rehoboamu ọba bá wí pẹlu ìtẹríba pé, “Olódodo ni Ọlọrun.” Nígbà tí Ọlọrun rí i pé wọ́n ti ronupiwada, ó sọ fún wolii Ṣemaaya pé, níwọ̀n ìgbà tí wọ́n ti rẹ ara wọn sílẹ̀, òun kò ní pa wọ́n run mọ́, ṣugbọn òun óo gbà wọ́n sílẹ̀ díẹ̀. Òun kò ní fi agbára lo Ṣiṣaki láti rọ̀jò ibinu òun sórí Jerusalẹmu. Sibẹsibẹ wọn yóo jẹ́ ẹrú rẹ̀, kí wọ́n lè mọ ìyàtọ̀ ninu pé kí wọ́n sin òun OLUWA, ati kí wọ́n sin ìjọba àwọn ilẹ̀ mìíràn. Ṣiṣaki bá gbógun ti Jerusalẹmu, ó kó gbogbo ìṣúra ilé OLUWA lọ, ati ti ààfin ọba patapata, ati apata wúrà tí Solomoni ṣe. Nítorí náà, Rehoboamu ṣe apata bàbà dípò wọn, ó sì fi wọ́n sábẹ́ àkóso olùṣọ́ ààfin. Nígbàkúùgbà tí ọba bá lọ sí ilé OLUWA, olùṣọ́ ààfin á ru apata náà ní iwájú rẹ̀, lẹ́yìn náà yóo kó wọn pada sí ibi tí wọ́n kó wọn pamọ́ sí. Nítorí pé Rehoboamu ronupiwada, OLUWA yí ibinu rẹ̀ pada, kò pa á run patapata mọ́. Nǹkan sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ dáradára ní ilẹ̀ Juda. Rehoboamu fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ ní Jerusalẹmu, agbára rẹ̀ sì pọ̀ sí i. Ọmọ ọdún mọkanlelogoji ni nígbà tí ó jọba. Ó jọba fún ọdún mẹtadinlogun ní Jerusalẹmu, ìlú tí OLUWA yàn láàrin àwọn ẹ̀yà yòókù, pé kí wọ́n ti máa sin òun. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Naama, ará Amoni. Rehoboamu ṣe nǹkan burúkú, nítorí pé kò fi ọkàn sí ati máa rìn ní ìlànà OLUWA. Gbogbo ohun tí Rehoboamu ṣe, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ni a kọ sinu ìwé ìtàn wolii Ṣemaaya, ati sinu ìwé Ido aríran. Nígbà gbogbo ni ogun máa ń wà láàrin Rehoboamu ati Jeroboamu. Nígbà tí Rehoboamu kú, wọ́n sin ín sí ìlú Dafidi, níbi ibojì àwọn baba rẹ̀. Abija ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Ní ọdún kejidinlogun ìjọba Jeroboamu ni Abija jọba ní ilẹ̀ Juda. Ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹta. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Mikaya, ọmọ Urieli ará Gibea. Nígbà kan, ogun bẹ́ sílẹ̀ láàrin Abija ati Jeroboamu. Abija kó ogún ọ̀kẹ́ (400,000) akọni ọmọ ogun jọ láti bá Jeroboamu jagun. Jeroboamu náà kó ogoji ọ̀kẹ́ (800,000) akọni ọmọ ogun jọ. Abija gun orí òkè Semaraimu tí ó wà ní agbègbè olókè Efuraimu lọ. Ó kígbe lóhùn rara, ó ní: “Gbọ́ mi, ìwọ Jeroboamu ati gbogbo ẹ̀yin eniyan Israẹli, ṣé ẹ ẹ̀ mọ̀ pé OLUWA Ọlọrun Israẹli ti fi iyọ̀ bá Dafidi dá majẹmu ayérayé pé àtìrandíran rẹ̀ ni yóo máa jọba lórí Israẹli títí lae? Sibẹsibẹ, Jeroboamu, ọmọ Nebati, iranṣẹ Solomoni, ọmọ Dafidi, dìde, ó ṣọ̀tẹ̀ sí Solomoni, oluwa rẹ̀. Ó sì lọ kó àwọn jàǹdùkú ati àwọn aláìníláárí eniyan kan jọ, wọ́n pe Rehoboamu ọmọ Solomoni níjà. Rehoboamu jẹ́ ọmọde nígbà náà, kò sì ní ìrírí tó láti dojú ìjà kọ wọ́n. Nisinsinyii, ẹ rò pé ẹ lè dojú ìjà kọ ìjọba OLUWA, tí ó gbé lé àwọn ọmọ Dafidi lọ́wọ́; nítorí pé ẹ pọ̀ ní iye ati pé ẹ ní ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù tí Jeroboamu fi wúrà ṣe tí ó pè ní ọlọrun yín? Ẹ ti lé àwọn alufaa OLUWA kúrò lọ́dọ̀ yín: àwọn ọmọ Aaroni, ati àwọn ọmọ Lefi. Ẹ yan alufaa mìíràn dípò wọn bí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè mìíràn ti ṣe. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá ti mú akọ mààlúù tabi aguntan meje wá, ẹ̀ ń yà á sí mímọ́ fún iṣẹ́ alufaa àwọn oriṣa tí kì í ṣe Ọlọrun. “Ṣugbọn ní tiwa, OLUWA Ọlọrun ni à ń sìn; a kò kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ọmọ Aaroni ni àwọn alufaa wa, àwọn ọmọ Lefi sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Ní àràárọ̀ ati ní alaalẹ́ ni wọ́n ń rú ẹbọ sísun, tí wọ́n sì ń sun turari. Wọ́n ń fi àkàrà ìfihàn sórí tabili wúrà. Ní alaalẹ́, wọ́n ń tan fìtílà wúrà lórí ọ̀pá fìtílà rẹ̀; nítorí àwa ń ṣe ohun tí Ọlọrun wa pa láṣẹ fún wa, ṣugbọn ẹ̀yin ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ọlọrun wà pẹlu wa, òun fúnrarẹ̀ ni aṣaaju wa. Àwọn alufaa rẹ̀ wà níhìn-ín láti fun fèrè láti pè wá kí á gbógun tì yín. Ẹ̀yin eniyan Israẹli, ẹ má ṣe bá OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín jà, nítorí ẹ kò ní borí.” Ṣugbọn Jeroboamu ti rán ọ̀wọ́ ọmọ ogun kan lọ láti kọlu àwọn ọmọ ogun Juda látẹ̀yìn. Àwọn ọmọ ogun Jeroboamu wà níwájú àwọn ọmọ ogun Juda, àwọn tí ó rán tí wọ́n sápamọ́ sì wà lẹ́yìn wọn. Nígbà tí Juda rí i pé ogun wà níwájú ati lẹ́yìn wọn, wọ́n ké pe OLUWA, àwọn alufaa sì fọn fèrè ogun. Àwọn ọmọ ogun Juda hó ìhó ogun, bí wọ́n sì ti kígbe ni Ọlọrun ṣẹgun Jeroboamu ati àwọn ọmọ ogun Israẹli fún Abija ati àwọn ọmọ ogun Juda. Àwọn ọmọ ogun Israẹli bá sá níwájú àwọn ọmọ ogun Juda, Ọlọrun sì fi wọ́n lé àwọn ọmọ ogun Juda lọ́wọ́. Abija ati àwọn ọmọ ogun Juda pa àwọn ọmọ ogun Israẹli ní ìpakúpa, tóbẹ́ẹ̀ tí ọ̀kẹ́ mẹẹdọgbọn (500,000) fi kú ninu àwọn akọni ọmọ ogun Israẹli. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ilẹ̀ Juda ṣe tẹ orí àwọn ọmọ Israẹli ba tí wọ́n sì ṣẹgun wọn, nítorí pé àwọn ọmọ Juda gbẹ́kẹ̀lé OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn. Abija lé Jeroboamu, ó sì gba ìlú Bẹtẹli, ati Jeṣana, ati Efuroni ati àwọn ìletò tí ó yí wọn ká lọ́wọ́ rẹ̀. Jeroboamu kò sì lè gbérí ní àkókò Abija. Nígbà tí ó yá Ọlọrun lu Jeroboamu pa. Ṣugbọn agbára Abija bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ síi. Iyawo mẹrinla ni ó ní; ó sì bí ọmọkunrin mejilelogun ati ọmọbinrin mẹrindinlogun. Gbogbo nǹkan yòókù ti Abija ṣe ní àkókò ìjọba rẹ̀, ati ohun tí ó sọ, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn wolii Ido. Nígbà tí Abija ọba kú, wọ́n sin ín sinu ibojì àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Asa ọmọ rẹ̀ jọba lẹ́yìn rẹ̀. Ní àkókò rẹ̀, alaafia wà ní ilẹ̀ náà fún ọdún mẹ́wàá. Asa ṣe ohun tí ó dára, tí ó tọ́, tí ó sì dùn mọ́ OLUWA Ọlọrun rẹ̀. Ó mú inú Ọlọrun dùn. Ó kó àwọn pẹpẹ àjèjì ati àwọn pẹpẹ ìrúbọ wọn kúrò, ó wó àwọn òpó oriṣa wọn lulẹ̀, ó sì fọ́ ère Aṣera. Ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ Juda láti wá ojurere OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn ati láti pa òfin rẹ̀ mọ́. Ó kó gbogbo àwọn pẹpẹ ìrúbọ ati àwọn pẹpẹ tí wọ́n ti ń sun turari ní gbogbo àwọn ìlú Juda jáde. Alaafia sì wà ní àkókò ìjọba rẹ̀. Ó kọ́ àwọn ìlú olódi sí ilẹ̀ Juda nítorí pé alaafia wà ní gbogbo ilẹ̀ náà. Ní gbogbo ọdún rẹ̀ kò sí ogun, nítorí OLUWA fún wọn ní alaafia. Ó bá sọ fún gbogbo ọmọ ilẹ̀ Juda pé, “Ẹ jẹ́ kí á kọ́ àwọn ìlú wọnyi, kí á mọ odi yí wọn ká pẹlu ilé ìṣọ́, kí á kan ìlẹ̀kùn sí àwọn ẹnubodè wọn, kí á sì fi àwọn ọ̀pá ìdábùú sí wọn. Ìkáwọ́ wa ni gbogbo ilẹ̀ náà wà, nítorí pé à ń ṣe ìfẹ́ OLUWA Ọlọrun wa. A ti wá ojurere rẹ̀, ó sì fún wa ní alaafia ní gbogbo ọ̀nà.” Wọ́n kọ́ àwọn ìlú náà, wọ́n sì ń ní ìtẹ̀síwájú. Asa ọba ní ọ̀kẹ́ mẹẹdogun (300,000) ọmọ ogun ní ilẹ̀ Juda, tí wọ́n di ihamọra pẹlu apata ati ọ̀kọ̀ ati ọ̀kẹ́ mẹrinla (280,000) láti Bẹnjamini tí wọ́n di ihamọra pẹlu apata ati ọrun. Gbogbo wọn ni a ti kọ́ ní ogun jíjà tí wọ́n sì jẹ́ akọni. Sera, ará Etiopia, gbógun tì wọ́n pẹlu ẹgbẹrun lọ́nà ẹgbẹrun (1,000,000) ọmọ ogun ati ọọdunrun (300) kẹ̀kẹ́ ogun. Wọ́n sì jagun títí dé Mareṣa. Asa jáde lọ láti bá a jà. Olukuluku tẹ́ ibùdó ogun rẹ̀ sí àfonífojì Sefata ní Mareṣa. Asa ké pe OLUWA Ọlọrun rẹ̀, ó ní, “OLUWA, kò sí olùrànlọ́wọ́ tí ó dàbí rẹ nítorí pé o lè ran àwọn ọmọ ogun tí wọn kò lágbára lọ́wọ́ láti ṣẹgun àwọn tí wọ́n lágbára. Ràn wá lọ́wọ́, OLUWA Ọlọrun wa, nítorí pé ìwọ ni a gbẹ́kẹ̀lé. Ní orúkọ rẹ ni a jáde láti wá bá ogun ńlá yìí jà. OLUWA, ìwọ ni Ọlọrun wa, má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣẹgun rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe ṣẹgun àwọn ará Etiopia fún Asa ati àwọn ọmọ Juda, àwọn ará Etiopia sì sá. Asa ati àwọn ogun rẹ̀ lé wọn títí dé Gerari. Ọpọlọpọ àwọn ará Etiopia sì kú tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò lè gbá ara wọn jọ mọ́; wọn sì parun patapata níwájú OLUWA ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Àwọn ọmọ ogun Juda sì kó ọpọlọpọ ìkógun. Wọ́n run gbogbo ìlú tí ó wà ní agbègbè Gerari, nítorí pé ẹ̀rù OLUWA ba àwọn ará ibẹ̀. Wọ́n fi ogun kó gbogbo àwọn ìlú náà nítorí pé ìkógun pọ̀ ninu wọn. Wọ́n wó gbogbo àgọ́ àwọn tí ń sin mààlúù, wọ́n sì kó ọpọlọpọ aguntan ati ràkúnmí wọn pada sí Jerusalẹmu. Ẹ̀mí Ọlọrun bà lé Asaraya ọmọ Odedi. Ó lọ pàdé Asa, ó wí fún un pé, “Gbọ́ mi, ìwọ Asa, ati gbogbo ẹ̀yin ọmọ Juda ati ti Bẹnjamini, OLUWA wà pẹlu yín níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin náà bá wà pẹlu rẹ̀. Bí ẹ bá wá a, ẹ óo rí i. Ṣugbọn bí ẹ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, òun náà yóo kọ̀ yín sílẹ̀. Ọjọ́ pẹ́, tí Israẹli ti wà láìní Ọlọrun òtítọ́, wọn kò ní alufaa tí ń kọ́ ni, wọn kò sì ní òfin. Ṣugbọn nígbà tí ìyọnu dé, wọ́n yipada sí OLUWA Ọlọrun Israẹli. Wọ́n wá OLUWA, wọ́n sì rí i. Ní àkókò náà, kò sí ìbàlẹ̀ ọkàn fún àwọn tí wọn ń jáde ati àwọn tí wọ́n ń wọlé, nítorí ìdààmú ńlá dé bá àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà. Orílẹ̀-èdè kan ń pa ekeji run, ìlú kan sì ń pa ekeji rẹ́, nítorí Ọlọrun mú oniruuru ìpọ́njú bá wọn. Ṣugbọn, ẹ̀yin ní tiyín, ẹ má ṣe bẹ̀rù, ẹ mọ́kàn le, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí ó rẹ̀ yín, nítorí iṣẹ́ yín yóo ní èrè.” Nígbà tí Asa gbọ́ àsọtẹ́lẹ̀ tí Asaraya ọmọ Odedi sọ, ó mọ́kàn le. Ó kó gbogbo ère kúrò ní gbogbo ilẹ̀ Juda ati gbogbo ilẹ̀ Bẹnjamini ati ní gbogbo àwọn ìlú tí wọ́n gbà ní agbègbè olókè Efuraimu. Ó tún pẹpẹ OLUWA tí ó wà níwájú yàrá àbáwọlé ilé OLUWA ṣe. Ó kó gbogbo àwọn ọmọ Juda ati àwọn ọmọ Bẹnjamini jọ, ati àwọn tí wọ́n wá láti Efuraimu, Manase ati Simeoni, tí wọ́n jẹ́ àlejò láàrin wọn. Nítorí pé ọpọlọpọ eniyan láti ilẹ̀ Israẹli ni wọ́n ti sá wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nígbà tí wọ́n rí i pé OLUWA Ọlọrun rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀. Wọ́n péjọ ní Jerusalẹmu ní oṣù kẹta ọdún kẹẹdogun ìjọba Asa. Wọ́n mú ẹẹdẹgbẹrin (700) mààlúù ati ẹẹdẹgbaarin (7,000) aguntan ninu ìkógun tí wọ́n kó, wọ́n fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun baba wọn. Wọ́n dá majẹmu pé àwọn yóo máa sin OLUWA Ọlọrun baba àwọn tọkàntọkàn àwọn; ati pé ẹnikẹ́ni tí kò bá sin OLUWA Ọlọrun Israẹli, ìbáà ṣe àgbà tabi ọmọde, ọkunrin tabi obinrin, pípa ni àwọn yóo pa á. Wọ́n fi igbe búra ní orúkọ OLUWA pẹlu ariwo ati fèrè. Inú gbogbo Juda sì dùn sí ẹ̀jẹ́ náà, nítorí pé tọkàntọkàn ni wọ́n fi jẹ́ ẹ. Tọkàntọkàn ni wọ́n fi ń sin Ọlọrun. Ọlọrun gba ìsìn wọn, ó sì fún wọn ní alaafia ní gbogbo ọ̀nà. Asa ọba, yọ Maaka ìyá rẹ̀ àgbà pàápàá kúrò ní ipò ìyá ọba, nítorí pé ó gbẹ́ ère ìríra kan fún oriṣa Aṣera. Asa wó ère náà lulẹ̀, ó gé e wẹ́lẹwẹ̀lẹ, ó sì dáná sun ún ní odò Kidironi. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Asa kò wó gbogbo àwọn pẹpẹ ìrúbọ palẹ̀ ní ilẹ̀ Israẹli, sibẹsibẹ kò ní ẹ̀bi ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. Ó kó àwọn nǹkan tí Abija, baba rẹ̀, ti yà sí mímọ́ fún Ọlọrun lọ sinu tẹmpili pẹlu gbogbo nǹkan tí òun pàápàá ti yà sí mímọ́: fadaka, wúrà, ati àwọn ohun èlò. Kò sí ogun mọ́ rárá títí tí ó fi di ọdún karundinlogoji ìjọba Asa. Ní ọdún kẹrindinlogoji ìjọba Asa, ní ilẹ̀ Juda, Baaṣa ọba Israẹli gbógun ti Juda, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mọ odi Rama láti dí ojú ọ̀nà tí ó lọ sí ilẹ̀ Juda, kí ẹnikẹ́ni má baà lè lọ sí ọ̀dọ̀ Asa, ọba Juda, kí àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ má sì lè jáde. Nítorí náà, Asa kó fadaka ati wúrà láti ilé ìṣúra ilé OLUWA ati láti ààfin ranṣẹ sí Benhadadi, ọba Siria tí ó ń gbé Damasku, ó ranṣẹ sí i pé: “Jẹ́ kí àjọṣepọ̀ wà láàrin wa gẹ́gẹ́ bí ó ti wà láàrin àwọn baba wa. Fadaka ati wúrà yìí ni mo fi ta ọ́ lọ́rẹ; pa majẹmu tí ó wà láàrin ìwọ ati Baaṣa ọba Israẹli tì, kí ó baà lè kó ogun rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi.” Benhadadi gba ọ̀rọ̀ Asa, ó bá rán àwọn ọ̀gágun rẹ̀ jáde láti lọ gbógun ti àwọn ìlú Israẹli. Wọ́n ṣẹgun Ijoni, Dani, Abeli Maimu ati gbogbo ìlú tí wọ́n kó ìṣúra pamọ́ sí ní ilẹ̀ Nafutali. Nígbà tí Baaṣa gbọ́ ohun tí ń ṣẹlẹ̀, ó dáwọ́ odi Rama tí ó ń mọ dúró. Asa bá kó àwọn eniyan jọ jákèjádò Juda, wọ́n lọ kó òkúta ati pákó tí Baaṣa fi ń kọ́ Rama, wọ́n lọ fi kọ́ Geba ati Misipa. Nígbà náà ni Hanani aríran, wá sọ́dọ̀ Asa, ọba Juda, ó wí fún un pé, “Nítorí pé o gbẹ́kẹ̀lé ọba Siria, dípò kí o gbẹ́kẹ̀lé OLUWA Ọlọrun rẹ, àwọn ogun Siria ti bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ. Ṣebí ogun Etiopia ati Libia lágbára gidigidi? Ṣebí wọ́n ní ọpọlọpọ kẹ̀kẹ́ ogun ati ẹlẹ́ṣin? Ṣugbọn nítorí pé o gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, ó fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí wọn. Nítorí ojú OLUWA ń lọ síwá sẹ́yìn ní gbogbo ayé láti fi agbára rẹ̀ hàn fún àwọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí i. Ìwà òmùgọ̀ ni èyí tí o hù yìí; nítorí pé láti ìsinsìnyìí lọ nígbàkúùgbà ni o óo máa jagun.” Ọ̀rọ̀ yìí mú kí inú bí Asa sí wolii Hanani, ó sì kan ààbà mọ́ ọn lẹ́sẹ̀ ninu túbú, nítorí inú bí i sí i fún ohun tí ó sọ. Asa ọba fi ìyà jẹ àwọn kan ninu àwọn ará ìlú ní àkókò náà. Gbogbo nǹkan tí Asa ọba ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ni a kọ sinu ìwé ìtàn àwọn ọba Juda ati Israẹli. Ní ọdún kọkandinlogoji ìjọba Asa, àrùn burúkú kan mú un lẹ́sẹ̀, àrùn náà pọ̀ pupọ. Sibẹsibẹ, ninu àìsàn náà kàkà kí ó ké pe OLUWA fún ìwòsàn, ọ̀dọ̀ àwọn oníṣègùn ni ó lọ. Asa kú ní ọdún kọkanlelogoji ìjọba rẹ̀. Wọ́n sin ín sinu ibojì òkúta tí ó gbẹ́ fúnrarẹ̀ ní ìlú Dafidi. Wọ́n tẹ́ ẹ sórí àkéte, tí ó kún fún oniruuru turari tí àwọn tí wọ́n ń ṣe turari ṣe. Wọ́n sì dá iná ńlá kan láti ṣọ̀fọ̀ rẹ̀. Jehoṣafati ọmọ rẹ̀ ni ó jọba lẹ́yìn rẹ̀; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbáradì láti dojú ìjà kọ Israẹli. Ó kó àwọn ọmọ ogun sí gbogbo àwọn ìlú olódi Juda, ó yan olórí ogun fún wọn ní ilẹ̀ Juda ati ní ilẹ̀ Efuraimu tí Asa baba rẹ̀ gbà. OLUWA wà pẹlu Jehoṣafati nítorí pé ó tẹ̀lé àpẹẹrẹ ìgbà ọ̀dọ̀ Dafidi, baba rẹ̀; kò sì bọ oriṣa Baali. Ṣugbọn ó ń sin Ọlọrun àwọn baba rẹ̀, ó pa òfin Ọlọrun mọ́, kò sì tẹ̀lé ìṣe àwọn ọmọ Israẹli. Nítorí náà OLUWA fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀, gbogbo àwọn ọmọ Juda sì ń san owó orí fún un. Nítorí náà ó di ọlọ́rọ̀ ati ọlọ́lá. Ó fi ìgboyà rìn ní ọ̀nà OLUWA, ó wó gbogbo pẹpẹ oriṣa, ó sì gé àwọn ère Aṣera káàkiri gbogbo ilẹ̀ Juda. Ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó pe àwọn marun-un ninu àwọn ìjòyè rẹ̀: Benhaili, Ọbadaya, ati Sakaraya, Netaneli, ati Mikaya, ó rán wọn jáde láti máa kọ́ àwọn eniyan ní ilẹ̀ Juda. Àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n bá wọn lọ ni: Ṣemaaya, Netanaya, ati Sebadaya; Asaheli, Ṣemiramotu, ati Jehonatani; Adonija, Tobija ati Tobadonija. Àwọn alufaa tí wọ́n tẹ̀lé wọn ni Eliṣama ati Jehoramu. Wọ́n lọ káàkiri gbogbo ilẹ̀ Juda pẹlu ìwé òfin lọ́wọ́ wọn, wọ́n ń kọ́ àwọn eniyan. OLUWA da jìnnìjìnnì bo gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n yí Juda ká, wọn kò sì gbógun ti Jehoṣafati. Àwọn kan ninu àwọn ará Filistia mú ẹ̀bùn ati fadaka wá fún Jehoṣafati gẹ́gẹ́ bíi ìṣákọ́lẹ̀. Àwọn ará Arabia náà sì mú ẹgbaarin ó dín ọọdunrun (7,700) àgbò, ati ẹgbaarin ó dín ọọdunrun (7,700) òbúkọ wá. Bẹ́ẹ̀ ni Jehoṣafati ṣe bẹ̀rẹ̀ sí lágbára sí i, ó kọ́ àwọn ilé ìṣọ́ ati àwọn ìlú tí wọn ń kó ìṣúra pamọ́ sí ní Juda; ó ní ilé tí wọn ń kó nǹkan pamọ́ sí ní àwọn ìlú ńláńlá Juda. Ó sì ní àwọn akọni ọmọ ogun ní Jerusalẹmu. Iye àwọn ọmọ ogun tí ó kó jọ nìyí gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: Adinai ni olórí ogun ẹ̀yà Juda, ó sì ní ọ̀kẹ́ mẹẹdogun (300,000) akọni ọmọ ogun lábẹ́ rẹ̀. Olórí ogun tí ó pọwọ́ lé e ni Jehohanani, ó ní ọ̀kẹ́ mẹrinla (280,000) ọmọ ogun lábẹ́ rẹ̀. Olórí ogun kẹta ni Amasaya, ọmọ Sikiri, ẹni tí ó yọ̀ǹda ara rẹ̀ fún iṣẹ́ OLUWA, ó ní ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000) akọni ọmọ ogun. Àwọn olórí ogun láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini ni: Eliada, akọni ọmọ ogun, ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000) àwọn ọmọ ogun tí wọn ń lo apata ati ọrun ni wọ́n wà lábẹ́ rẹ̀. Igbákejì ni Jehosabadi; òun náà ní ọ̀kẹ́ mẹsan-an (180,000) ọmọ ogun tí wọ́n ti dira ogun, lábẹ́ rẹ̀. Gbogbo àwọn wọnyi ni wọ́n wà lábẹ́ ọba ní Jerusalẹmu, láìka àwọn tí ó fi sí àwọn ìlú olódi ní gbogbo ilẹ̀ Juda. Nígbà tí Jehoṣafati ọba Juda di ọlọ́rọ̀ ati olókìkí, ó fẹ́ ọmọ Ahabu kí ó lè ní àjọṣepọ̀ pẹlu Ahabu. Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, Jehoṣafati lọ sí ìlú Samaria láti bẹ Ahabu wò. Láti dá Jehoṣafati lọ́lá pẹlu àwọn tí wọ́n bá a wá, Ahabu pa ọpọlọpọ aguntan ati mààlúù fún àsè. Ó rọ Jehoṣafati láti bá òun lọ gbógun ti ìlú Ramoti Gileadi. Ahabu, ọba Israẹli bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé o óo bá mi lọ gbógun ti Ramoti Gileadi?” Jehoṣafati dáhùn pé, “Tìrẹ ni èmi ati àwọn eniyan mi, a óo bá ọ lọ jagun náà.” Ṣugbọn Jehoṣafati sọ fún ọba Israẹli pé, “Jẹ́ kí á kọ́kọ́ bèèrè lọ́wọ́ OLUWA ná.” Nítorí náà, Ahabu pe gbogbo àwọn Wolii jọ, gbogbo wọn jẹ́ irinwo (400). Ó bi wọ́n pé, “Ṣé kí á lọ gbógun ti Ramoti Gileadi tabi kí á má lọ?” Wọ́n dáhùn pé, “Lọ gbógun tì í, Ọlọrun yóo fún ọ ní ìṣẹ́gun.” Ṣugbọn Jehoṣafati bèèrè lọ́wọ́ Ahabu pé, “Ṣé kò sí wolii OLUWA mìíràn mọ́ tí a lè bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀?” Ahabu dáhùn pé, “Ó ku ọ̀kan tí à ń pè ní Mikaya, ọmọ Imila tí a lè bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Ṣugbọn mo kórìíra rẹ̀, nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ rere kan kò ti ẹnu rẹ̀ jáde sí mi rí, àfi kìkì burúkú.” Jehoṣafati dáhùn, ó ní, “Má sọ bẹ́ẹ̀.” Nítorí náà, Ahabu ọba pe ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ rẹ̀ kí ó lọ pe Mikaya wá kíákíá. Àwọn ọba mejeeji gúnwà lórí ìtẹ́ wọn, ní ibi ìpakà, ní àbáwọ bodè Samaria, gbogbo àwọn wolii sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀ níwájú wọn. Ọ̀kan ninu àwọn wolii tí à ń pè ní Sedekaya, ọmọ Kenaana ṣe àwọn ìwo irin kan, ó sì sọ fún Ahabu pé, “OLUWA ní, pẹlu àwọn ìwo wọnyi ni o óo fi bi àwọn ará Siria sẹ́yìn, títí tí o óo fi run wọ́n patapata.” Àwọn wolii yòókù ń sọ bákan náà, wọ́n ń wí pé, “Lọ gbógun ti Ramoti Gileadi, o óo ṣẹgun. OLUWA yóo fi wọ́n lé ọba lọ́wọ́.” Iranṣẹ tí ó lọ pe Mikaya sọ fún un pé, “Àsọtẹ́lẹ̀ kan náà ni gbogbo àwọn wolii ń sọ, pé ọba yóo ṣẹgun, ìwọ náà sọ bẹ́ẹ̀.” Ṣugbọn Mikaya dáhùn pé, “Mo fi orúkọ OLUWA búra pé ohun tí Ọlọrun bá sọ fún mi pé kí n sọ ni n óo sọ.” Nígbà tí ó dé iwájú Ahabu, Ahabu bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Mikaya, ṣé kí á lọ gbógun ti Ramoti Gileadi tabi kí á má ṣe lọ?” Mikaya dáhùn pé, “Ẹ lọ gbógun tì í, OLUWA yóo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́, ẹ óo sì ṣẹgun.” Ṣugbọn Ahabu bi í pé, “Ìgbà mélòó ni mo níláti mú ọ búra pé kí o máa sọ òtítọ́ fún mi ní orúkọ OLUWA?” Mikaya bá sọ pé, “Mo rí i tí gbogbo ọmọ ogun Israẹli fọ́n káàkiri lórí òkè, bí aguntan tí kò ní olùṣọ́. OLUWA bá sọ pé, ‘Àwọn eniyan wọnyi kò ní olórí. Jẹ́ kí olukuluku máa lọ sí ilé rẹ̀ ní alaafia.’ ” Ọba Israẹli wí fún Jehoṣafati pé, “Ṣé o ranti pé mo ti sọ pé kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere fún mi rí? Àsọtẹ́lẹ̀ burúkú nìkan ni òun máa ń sọ.” Mikaya bá dáhùn pé, “Gbọ́ ohun tí OLUWA sọ! Mo rí OLUWA, ó jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀, àwọn ogun ọ̀run sì wà ní apá ọ̀tún ati apá òsì rẹ̀. OLUWA bèèrè pé, ‘Ta ni yóo lọ tan Ahabu, ọba Israẹli, kí ó lè lọ sí Ramoti Gileadi, kí ó sì kú níbẹ̀.’ Bí àwọn kan tí ń sọ nǹkankan, ni àwọn mìíràn ń sọ nǹkan mìíràn. Nígbà náà ni ẹ̀mí kan jáde, ó sì dúró níwájú OLUWA, ó ní, ‘N óo lọ tan Ahabu jẹ.’ OLUWA bá bèèrè pé, ‘Ọgbọ́n wo ni o fẹ́ dá?’ Ẹ̀mí náà dáhùn pé, ‘N óo lọ sọ gbogbo àwọn wolii Ahabu di wolii èké.’ OLUWA bá dá a lóhùn pé, ‘Ìwọ ni kí o lọ tàn án jẹ, o óo sì ṣe àṣeyọrí, lọ ṣe bí o ti wí.’ ” Mikaya ní, “OLUWA ni ó mú kí àwọn wolii rẹ wọnyi máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké, ṣugbọn àjálù burúkú ni OLUWA ti pinnu pé yóo dé bá ọ.” Nígbà náà ni Sedekaya, ọmọ Kenaana súnmọ́ Mikaya, ó gbá a létí, ó wí pé, “Nígbà wo ni ẹ̀mí OLUWA fi mí sílẹ̀ tí ó wá ń bá ọ sọ̀rọ̀?” Mikaya dáhùn pé, “Ojú rẹ yóo já a ní ọjọ́ náà, nígbà tí o bá lọ sá pamọ́ sí kọ̀rọ̀ yàrá.” Nígbà náà ni Ahabu ọba pàṣẹ pé kí wọ́n mú Mikaya lọ sọ́dọ̀ Amoni, gomina ìlú ati sọ́dọ̀ Joaṣi, ọmọ ọba, kí wọ́n sì sọ fún wọn pé: Ẹ ju ọkunrin yìí sẹ́wọ̀n, kí wọ́n sì máa fún un ní omi ati burẹdi nìkan títí òun óo fi pada dé ní alaafia. Mikaya dáhùn pé, “Tí o bá pada dé ní alaafia, a jẹ́ pé kì í ṣe OLUWA ni ó gba ẹnu mi sọ̀rọ̀.” Ó sì tún sọ siwaju sí i pé, kí olukuluku fetí sí ohun tí òun wí dáradára. Ahabu ọba Israẹli ati Jehoṣafati ọba Juda lọ gbógun ti Ramoti Gileadi. Ahabu sọ fún Jehoṣafati pé, “Bí a ti ń lọ sógun yìí, n óo yí ara pada. Ṣugbọn ìwọ ní tìrẹ, wọ aṣọ ìgúnwà rẹ.” Ọba Israẹli bá yíra pada, ó lọ sí ojú ogun. Ọba Siria ti pàṣẹ fún àwọn ọ̀gágun tí wọn ń ṣàkóso àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe bá ẹnikẹ́ni jà bíkòṣe ọba Israẹli nìkan. Nítorí náà, nígbà tí wọ́n rí Jehoṣafati, wọ́n rò pé ọba Israẹli ni, wọ́n bá yíjú sí i láti bá a jà. Jehoṣafati bá bẹ̀rẹ̀ sí kígbe, OLUWA sì gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá. Nígbà tí àwọn ọ̀gágun náà rí i pé kì í ṣe Ahabu, ọba Israẹli, wọ́n pada lẹ́yìn rẹ̀. Ṣugbọn ọmọ ogun Siria kan déédé ta ọfà rẹ̀, ọfà náà sì bá Ahabu ọba níbi tí ìgbàyà ati ihamọra rẹ̀ ti pàdé. Ó bá kígbe sí ẹni tí ó ru ihamọra rẹ̀ pé, “Mo ti fara gbọgbẹ́, yipada kí o gbé mi kúrò lójú ogun.” Ogun gbóná ní ọjọ́ náà, Ahabu ọba bá rá pálá dìde dúró, wọ́n fi ọwọ́ mú un ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó kọjú sí ogun Siria. Ṣugbọn nígbà tí oòrùn ń wọ̀ lọ, ó kú. Jehoṣafati ọba Juda pada ní alaafia sí ààfin rẹ̀ ní Jerusalẹmu. Ṣugbọn Jehu, aríran, ọmọ Hanani lọ pàdé rẹ̀, ó sọ fún un pé, “Ṣé ó dára kí o máa ran eniyan burúkú lọ́wọ́, kí o fẹ́ràn àwọn tí wọ́n kórìíra OLUWA? Nítorí èyí, ibinu OLUWA ru sí ọ. Sibẹsibẹ àwọn nǹkankan wà tí o ṣe tí ó dára, o run àwọn ère oriṣa Aṣera ní ilẹ̀ yìí, o sì ti ṣe ọkàn rẹ gírí láti tẹ̀lé Ọlọ́run.” Jerusalẹmu ni Jehoṣafati ń gbé, ṣugbọn a máa lọ jákèjádò ilẹ̀ náà láàrin àwọn ọmọ Israẹli, láti Beeriṣeba títí dé agbègbè olókè Efuraimu, a máa káàkiri láti yí wọn lọ́kàn pada sí OLUWA Ọlọrun baba wọn. Ó yan àwọn adájọ́ ní gbogbo àwọn ìlú olódi ní ilẹ̀ Juda. Ó kìlọ̀ fún wọn ó ní, “Ẹ ṣọ́ra gan-an, nítorí pé kì í ṣe eniyan ni ẹ̀ ń ṣiṣẹ́ fún, OLUWA ni. Ẹ sì ranti pé OLUWA wà lọ́dọ̀ yín bí ẹ ti ń ṣe ìdájọ́. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù OLUWA, kí ẹ sì ṣọ́ra pẹlu àwọn nǹkan tí ẹ ó máa ṣe, nítorí pé OLUWA Ọlọrun wa kì í yí ìdájọ́ po, kì í ṣe ojuṣaaju, bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.” Jehoṣafati tún yan àwọn kan ní Jerusalẹmu ninu àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn alufaa ati àwọn baálé baálé ní Israẹli, láti máa fi òfin OLUWA ṣe ìdájọ́ ati láti máa yanjú ẹjọ́ tí kò bá di àríyànjiyàn. Ó kìlọ̀ fún wọn, ó ní “Ohun tí ẹ gbọdọ̀ máa fi tọkàntọkàn ṣe, pẹlu ìbẹ̀rù OLUWA ati òtítọ́ nìyí: Nígbàkúùgbà tí àwọn arakunrin yín bá mú ẹjọ́ wá siwaju yín láti ìlú kan, kì báà ṣe ti ìtàjẹ̀sílẹ̀, tabi ti nǹkan tí ó jẹ mọ́ òfin, tabi àṣẹ, tabi ìlànà, ẹ níláti ṣe àlàyé fún wọn kí wọ́n má baà jẹ̀bi níwájú OLUWA, kí ibinu OLUWA má baà wá sórí ẹ̀yin náà ati àwọn arakunrin yín. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ gbọdọ̀ máa ṣe kí ẹ má baà jẹ̀bi. Amaraya, olórí alufaa ni alabojuto yín ninu gbogbo nǹkan tí ó bá jẹ mọ́ OLUWA. Sebadaya, ọmọ Iṣimaeli, tí ó jẹ́ gomina ní Juda ni alabojuto lórí ọ̀rọ̀ ìlú, àwọn ọmọ Lefi yóo sì máa ṣe òjíṣẹ́ yín. Ẹ má bẹ̀rù. Kí OLUWA wà pẹlu ẹ̀yin tí ẹ dúró ṣinṣin.” Lẹ́yìn èyí, àwọn ará Moabu, ati àwọn ará Amoni, ati díẹ̀ ninu àwọn ará Meuni kó ara wọn jọ láti bá Jehoṣafati jagun. Àwọn kan wá sọ fún Jehoṣafati pé ogun ńlá kan ń bọ̀ wá jà á láti Edomu ní òdìkejì òkun. Wọ́n sọ pé àwọn ọ̀tá náà ti dé Hasasoni Tamari, (tí a tún ń pè ní Engedi). Ẹ̀rù ba Jehoṣafati gidigidi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wá ojú OLUWA, ó kéde jákèjádò ilẹ̀ Juda pé kí wọ́n gbààwẹ̀. Àwọn eniyan péjọ láti gbogbo ìlú Juda, wọ́n wá bèèrè ìrànlọ́wọ́ OLUWA. Jehoṣafati bá dìde dúró láàrin àwọn tí wọ́n ti Juda ati Jerusalẹmu wá sinu tẹmpili, níbi tí wọ́n péjọ sí níwájú gbọ̀ngàn tuntun, ó ní, “OLUWA Ọlọrun àwọn baba wa, ṣebí ìwọ ni Ọlọrun ọ̀run. Ìwọ ni o ni àkóso ìjọba gbogbo orílẹ̀-èdè. Agbára ati ipá wà ní ìkáwọ́ rẹ, kò sì sí ẹni tí ó tó dojú kọ ọ́. Ṣebí ìwọ, Ọlọrun wa, ni o lé gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbé ilẹ̀ yìí tẹ́lẹ̀ kúrò fún àwa ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, tí o sì fi ilẹ̀ náà fún arọmọdọmọ Abrahamu, ọ̀rẹ́ rẹ, títí lae? Wọ́n ti ń gbé ibẹ̀, wọ́n sì ti kọ́ ibi mímọ́ sibẹ fún ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ, nítorí pé tí ibi bá dé bá wa, tabi ìdájọ́, tabi àjàkálẹ̀ àrùn, tabi ìyàn, a óo dúró níwájú ilé yìí ati níwájú rẹ, nítorí orúkọ rẹ wà ninu ilé yìí. A óo ké pè ọ́ ninu ìyọnu wa, o óo gbọ́ tiwa, o óo sì gbà wá. “Nisinsinyii, wo àwọn ọmọ ogun Amoni, ati ti Moabu ati ti Òkè Seiri, àwọn tí o kò jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli bá jà nígbà tí wọ́n ń bọ̀ láti Ijipti, o kò jẹ́ kí wọ́n pa wọ́n run. Wò ó! Wọ́n ń fi burúkú san ire fún wa, wọ́n ń bọ̀ wá lé wa kúrò lórí ilẹ̀ rẹ, tí o fún wa bí ìní. Ọlọrun wa, dá wọn lẹ́jọ́. Nítorí pé agbára wa kò tó láti dojú kọ ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun wọn tí wọn ń kó bọ̀ wá bá wa jà. A kò mọ ohun tí a lè ṣe, ìwọ ni a gbójú sókè tí à ń wò.” Gbogbo àwọn ọkunrin Juda dúró níwájú OLUWA pẹlu àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn, àwọn aya wọn ati àwọn ọmọ wọn. Ẹ̀mí OLUWA bà lé Jahasieli, ọmọ Sakaraya, ọmọ Bẹnaya, ọmọ Jeieli, ọmọ Matanaya; ọmọ Lefi ni, láti inú ìran Asafu. Ó bá dìde dúró láàrin àwùjọ àwọn eniyan. Ó ní, “Ẹ fetí sí mi, gbogbo ẹ̀yin ará Juda ati ti Jerusalẹmu ati ọba Jehoṣafati, OLUWA ní kí ẹ má fòyà, kí ẹ má sì jẹ́ kí ọkàn yín rẹ̀wẹ̀sì nítorí ogun ńlá yìí; nítorí pé kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ ó ja ogun ńlá yìí, Ọlọrun ni. Ní ọ̀la, ẹ kógun lọ bá wọn; wọn yóo gba ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Sisi wá, ẹ óo rí wọn ní òpin àfonífojì ní apá ìlà oòrùn aṣálẹ̀ Jerueli. Ẹ kò ní jagun rárá, ẹ sá dúró ní ààyè yín, kí ẹ sì farabalẹ̀, ẹ óo sì rí bí OLUWA yóo ti gba ẹ̀yin ará Juda ati Jerusalẹmu là. Ẹ má fòyà, ẹ má sì jẹ́ kí ọkàn yín rẹ̀wẹ̀sì, Ẹ lọ kò wọ́n lójú lọ́la, OLUWA yóo wà pẹlu yín.” Jehoṣafati dojúbolẹ̀, gbogbo àwọn ará Juda ati àwọn ará Jerusalẹmu náà bá dojúbolẹ̀, wọ́n sì sin OLUWA. Ni àwọn ọmọ Lefi láti inú ìdílé Kohati ati ti Kora bá dìde, wọ́n gbóhùn sókè, wọ́n sì yin OLUWA Ọlọrun Israẹli. Ní kutukutu òwúrọ̀ ọjọ́ keji, àwọn eniyan náà lọ sí aṣálẹ̀ Tekoa. Bí wọ́n ti ń lọ, Jehoṣafati dúró, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gbọ́ ẹ̀yin ará Juda ati ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ẹ gba OLUWA Ọlọrun yín gbọ́, yóo fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, ẹ gba ohun tí àwọn wolii rẹ̀ wí gbọ́ pẹlu, ẹ óo sì ní ìṣẹ́gun.” Nígbà tí Jehoṣafati bá àwọn eniyan rẹ̀ jíròrò tán, ó yan àwọn tí wọn yóo máa kọrin ìyìn sí OLUWA; tí wọn yóo wọ aṣọ mímọ́, tí wọn yóo sì máa yìn ín bí wọn yóo ti máa lọ níwájú ogun, wọn yóo máa kọrin pé, “Ẹ yin OLUWA! Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ dúró laelae.” Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọrin ìyìn, OLUWA gbẹ̀yìn yọ sí àwọn ọmọ ogun Amoni, ati Moabu ati ti Òkè Seiri tí wọ́n wá bá àwọn eniyan Juda jà, ó sì tú wọn ká. Àwọn ọmọ ogun Amoni, ati Moabu gbógun ti àwọn ará Òkè Seiri wọ́n sì pa wọ́n run patapata. Lẹ́yìn náà, wọ́n dojú ìjà kọ ara wọn, wọ́n sì pa ara wọn run. Nígbà tí ogun Juda dé ilé ìṣọ́ tí ó wà ninu aṣálẹ̀, wọ́n wo àwọn ọ̀tá wọn, wọ́n sì rí i pé wọ́n ti kú sílẹ̀ lọ bẹẹrẹ; kò sí ẹni tí ó sá àsálà ninu wọn. Nígbà tí Jehoṣafati ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ láti kó ìkógun, wọ́n rí ọpọlọpọ mààlúù, ati ẹrù aṣọ ati nǹkan ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye. Wọ́n kó wọn títí ó fi sú wọn. Odidi ọjọ́ mẹta ni wọ́n fi kó ìkógun nítorí pé ó ti pọ̀ jù. Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n péjọ ní àfonífojì Beraka. Ibẹ̀ ni wọ́n ti yin OLUWA. Nítorí náà ni wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí pe ibẹ̀ ní Beraka títí di òní olónìí. Jehoṣafati kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pada sí Jerusalẹmu pẹlu ayọ̀ ìṣẹ́gun, nítorí pé OLUWA ti fún un ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀. Nígbà tí wọ́n dé Jerusalẹmu, wọ́n wọ inú tẹmpili lọ, pẹlu ìró hapu, ati ti dùùrù ati ti fèrè. Ẹ̀rù OLUWA ba ìjọba gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè nígbà tí wọ́n gbọ́ pé OLUWA bá àwọn ọ̀tá àwọn ọmọ Israẹli jagun. Nítorí náà Jehoṣafati jọba ní alaafia, nítorí pé Ọlọrun fún un ní ìsinmi ní gbogbo àyíká rẹ̀. Jehoṣafati jọba lórí Juda, ẹni ọdún marundinlogoji ni nígbà tí ó gorí oyè. Gbogbo ọdún tí ó lò lórí oyè jẹ́ ọdún mẹẹdọgbọn. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Asuba, ọmọ Ṣilihi. Ó ṣe dáradára gẹ́gẹ́ bí Asa, baba rẹ̀, ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA. Ṣugbọn kò pa àwọn pẹpẹ ìrúbọ run; àwọn eniyan kò tíì máa fi tọkàntọkàn sin Ọlọrun àwọn baba ńlá wọn. Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoṣafati ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ni a kọ sinu ìwé ìtàn Jehu ọmọ Hanani, tí ó jẹ́ apá kan ìtàn àwọn ọba Israẹli. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Jehoṣafati, ọba Juda lọ darapọ̀ mọ́ Ahasaya, ọba Israẹli, tí ó jẹ́ eniyan burúkú. Wọ́n jọ kan àwọn ọkọ̀ ojú omi tí yóo lọ sí ìlú Taṣiṣi. Wọ́n kan àwọn ọkọ̀ náà ní Esiongeberi. Elieseri ọmọ Dodafahu, ará Mareṣa fi àsọtẹ́lẹ̀ bá Jehoṣafati wí. Ó ní, “Nítorí pé o darapọ̀ mọ́ Ahasaya, OLUWA yóo ba ohun tí o ti ṣe tẹ́lẹ̀ jẹ́.” Gbogbo àwọn ọkọ̀ ojú omi náà rì, wọn kò sì lè lọ sí Taṣiṣi mọ́. Jehoṣafati kú, wọ́n sin ín pẹlu àwọn baba rẹ̀ ninu ibojì àwọn ọba ní ìlú Dafidi. Jehoramu, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Jehoramu ní arakunrin mẹfa, tí wọ́n jọ jẹ́ ọmọ Jehoṣafati, orúkọ wọn ni, Asaraya, Jehieli, ati Sakaraya, Asaraya, Mikaeli ati Ṣefataya. Baba wọn fún wọn ní ọpọlọpọ ẹ̀bùn: fadaka, wúrà ati àwọn nǹkan olówó iyebíye, pẹlu àwọn ìlú olódi ní Juda. Ṣugbọn Jehoramu ni ó fi ìjọba lé lọ́wọ́, nítorí pé òun ni àkọ́bí rẹ̀. Nígbà tí ó jọba tán, tí ó sì ti fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀, ó fi idà pa gbogbo àwọn arakunrin rẹ̀ ati díẹ̀ ninu àwọn olóyè ní Israẹli. Jehoramu jẹ́ ẹni ọdún mejilelọgbọn nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mẹjọ ní Jerusalẹmu. Ó tẹ̀ sí ọ̀nà burúkú tí àwọn ọba Israẹli rìn, ó ṣe bí ìdílé Ahabu ti ṣe, nítorí pé ọmọ Ahabu ni iyawo rẹ̀. Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA. Sibẹsibẹ OLUWA kò pa ìdílé Dafidi run nítorí majẹmu tí ó ti bá Dafidi dá, ati ìlérí tí ó ti ṣe pé ọmọ rẹ̀ ni yóo máa wà lórí oyè títí lae. Ní àkókò ìjọba Jehoramu ni Edomu ṣọ̀tẹ̀ sí Juda, wọ́n sì yan ọba fún ara wọn. Nítorí náà Jehoramu ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀ ati àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ lọ gbógun tì wọ́n. Ní òru, Jehoramu ati ogun rẹ̀ dìde, wọ́n fọ́ ogun Edomu tí ó yí wọn ká tàwọn ti kẹ̀kẹ́ ogun wọn, ati àwọn tí ń wà wọ́n. Láti ìgbà náà ni Edomu ti ń bá Juda ṣọ̀tẹ̀ títí di òní olónìí. Ní àkókò kan náà ni Libina ṣọ̀tẹ̀ sí Juda, ó sì gba òmìnira nítorí pé Jehoramu ti fi ọ̀nà OLUWA àwọn baba rẹ̀ sílẹ̀. Ó tilẹ̀ kọ́ àwọn pẹpẹ ìrúbọ káàkiri ní agbègbè olókè Juda. Ó fa àwọn ará Jerusalẹmu sinu aiṣododo, ó sì kó àwọn ọmọ Juda ṣìnà. Elija wolii kọ ìwé kan sí Jehoramu, ohun tí ó kọ sinu ìwé náà nìyí: “Gbọ́ bí OLUWA Ọlọrun Dafidi, baba rẹ, ti wí; ó ní, nítorí pé o kò tọ ọ̀nà tí Jehoṣafati baba rẹ tọ̀, tabi ti Asa, baba baba rẹ. Ṣugbọn ò ń hùwà bí àwọn ọba Israẹli, o sì ti fa àwọn Juda ati Jerusalẹmu sinu aiṣododo, bí ìdílé Ahabu ti ṣe fún Israẹli. Pataki jùlọ, o pa àwọn arakunrin rẹ, àwọn ọmọ baba rẹ, tí wọ́n tilẹ̀ sàn jù ọ́ lọ. Wò ó, OLUWA yóo fi àjàkálẹ̀ àrùn ṣe àwọn eniyan rẹ, ati àwọn ọmọ rẹ, ati àwọn aya rẹ ati gbogbo ohun tí o ní. Àrùn burúkú kan yóo kọlu ìwọ pàápàá, àrùn inú ni, yóo pọ̀, yóo sì pẹ́ lára rẹ títí tí ìfun rẹ yóo fi bẹ̀rẹ̀ sí tú jáde.” OLUWA mú kí inú àwọn ará Filistia ati ti àwọn ará Arabia, tí wọn ń gbé nítòsí àwọn ará Etiopia, ru sí Jehoramu. Wọ́n dó ti Juda, wọ́n gbógun tì wọ́n, wọ́n kó gbogbo ìṣúra tí ó wà ní ààfin lọ, pẹlu àwọn ọmọ Jehoramu ati àwọn iyawo rẹ̀. Kò ku ẹyọ ọmọ kan àfi èyí àbíkẹ́yìn tí ń jẹ́ Ahasaya. Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọnyi, OLUWA fi àrùn inú kan tí kò ṣe é wò bá Jehoramu jà. Lẹ́yìn ọdún keji tí àìsàn náà tí ń ṣe é, ìfun rẹ̀ tú síta, ó sì kú ninu ọpọlọpọ ìrora. Wọn kò dá iná ẹ̀yẹ fún un gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti máa ń ṣe níbi ìsìnkú àwọn baba rẹ̀. Ẹni ọdún mejilelọgbọn ni nígbà tí ó gorí oyè, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹjọ. Nígbà tí ó kú, kò sí ẹni tí ó sọkún, tabi tí ó ṣọ̀fọ̀ níbi òkú rẹ̀. Ìlú Dafidi ni wọ́n sin ín sí, ṣugbọn kì í ṣe ní ibojì àwọn ọba. Àwọn ọmọ ogun Arabia tí wọn ń jà káàkiri pa gbogbo àwọn ọmọ Jehoramu, ọba Juda, àfi Ahasaya, àbíkẹ́yìn rẹ̀. Nítorí náà àwọn ará Jerusalẹmu bá fi Ahasaya jọba lẹ́yìn Jehoramu. Ahasaya jẹ́ ẹni ọdún mejilelogoji, nígbà tí ó jọba; ó sì wà lórí oyè fún ọdún kan ní Jerusalẹmu. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Atalaya, ọmọ ọmọ Omiri. Ìwà burúkú ni òun náà ń hù bíi ti Ahabu, nítorí pé ìyá rẹ̀ ní ń darí rẹ̀ sí ọ̀nà ibi. Ohun tí ó ṣe burú lójú OLUWA bí ìdílé Ahabu ti ṣe, nítorí pé lẹ́yìn ikú baba rẹ̀, àwọn ará ilé Ahabu ni olùdámọ̀ràn rẹ̀, àwọn ni wọ́n fa ìṣubú rẹ̀. Ìmọ̀ràn wọn ni ó tẹ̀lé tí ó fi pa ogun tirẹ̀ pọ̀ mọ́ ti Joramu, ọba Israẹli, láti bá Hasaeli ọba Siria jagun ní Ramoti Gileadi. Àwọn ará Siria sì ṣá Joramu lọ́gbẹ́ lójú ogun náà, ó bá pada lọ sí ìlú Jesireeli láti wo ọgbẹ́ tí wọ́n ṣá a lójú ogun ní Rama nígbà tí ó ń bá Hasaeli ọba Siria jagun. Ahasaya, ọmọ Jehoramu, ọba Juda, sì lọ bẹ̀ ẹ́ wò ní Jesireeli nítorí ara rẹ̀ tí kò yá. Ọlọrun ti pinnu pé ìparun óo bá Ahasaya nígbà tí ó bá lọ bẹ Joramu wò. Nígbà tí ó wà níbẹ̀, òun pẹlu Joramu lọ pàdé Jehu ọmọ Nimṣi, ẹni tí OLUWA ti yàn pé òun ni yóo pa ìdílé Ahabu run. Nígbà tí Jehu dé láti pa ilé Ahabu run bí Ọlọrun ti fún un láṣẹ, ó pàdé àwọn ìjòyè Juda ati ọmọ arakunrin Ahasaya tí ó bá Ahasaya wá, ó bá pa wọ́n. Ó wá Ahasaya káàkiri títí; ní Samaria níbi tí ó sá pamọ́ sí ni wọ́n ti rí i mú, wọ́n bá mú un tọ Jehu wá, ó sì pa á. Wọ́n sin òkú rẹ̀, nítorí wọ́n ní, “Ọmọ ọmọ Jehoṣafati, ẹni tí ó fi tọkàntọkàn gbọ́ ti OLUWA ni.” Ní àkókò yìí, kò sí ẹnikẹ́ni ninu ìdílé Ahasaya tí ó lágbára tó láti jọba ilẹ̀ Juda. Nígbà tí Atalaya, ìyá Ahasaya rí i pé ọmọ òun ti kú, ó bẹ̀rẹ̀ sí pa gbogbo ìran ọba ní Juda. Ṣugbọn Jehoṣeba, ọmọbinrin Jehoramu ọba, tí ó jẹ́ iyawo Jehoiada alufaa, gbé Joaṣi ọmọ Ahasaya sá kúrò láàrin àwọn ọmọ ọba tí wọ́n fẹ́ pa, nítorí pé àbúrò rẹ̀ ni Joaṣi yìí. Ó bá fi òun ati olùtọ́jú rẹ̀ pamọ́ sinu yàrá kan. Bẹ́ẹ̀ ni Jehoṣeba ṣe gbé ọmọ náà pamọ́ fún Atalaya, tí kò fi rí i pa. Joaṣi wà pẹlu wọn níbi tí wọ́n gbé e pamọ́ sí ninu ilé OLUWA fún ọdún mẹfa tí Atalaya fi jọba ní ilẹ̀ náà. Ní ọdún keje Jehoiada alufaa mọ́kàn gírí, ó lọ bá àwọn marun-un ninu àwọn balogun dá majẹmu. Àwọn ni: Asaraya, ọmọ Jerohamu, Iṣimaeli ọmọ Jehohanani, Asaraya ọmọ Obedi, Maaseaya ọmọ Adaya ati Eliṣafati ọmọ Sikiri. Wọ́n lọ káàkiri gbogbo ilẹ̀ Juda, wọ́n lọ kó àwọn Lefi ati àwọn baálé baálé gbogbo ní Israẹli wá sí Jerusalẹmu. Gbogbo wọn pàdé ninu ilé Ọlọrun, wọ́n sì bá ọba dá majẹmu níbẹ̀. Jehoiada wí fún wọn pé, “Ẹ wò ó! Ọmọ ọba nìyí, ó tó àkókò láti fi jọba nisinsinyii, gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí OLUWA ṣe pé ìran Dafidi ni yóo máa jọba. Ohun tí ẹ óo ṣe nìyí: nígbà tí àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi bá kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi, ìdámẹ́ta ninu wọn yóo máa ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA, ìdámẹ́ta yóo wà ní ààfin ọba, ìdámẹ́ta tó kù yóo máa ṣọ́ Ẹnubodè Ìpìlẹ̀; gbogbo àwọn eniyan yóo sì péjọ sí gbọ̀ngàn ilé OLUWA. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọnú ilé OLUWA, àfi àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́. Àwọn lè wọlé nítorí pé wọ́n mọ́. Ṣugbọn àwọn eniyan tí ó kù gbọdọ̀ pa àṣẹ OLUWA mọ́. Àwọn ọmọ Lefi yóo yí ọba ká láti ṣọ́ ọ, olukuluku yóo mú ohun ìjà rẹ̀ lọ́wọ́, wọ́n gbọdọ̀ wà pẹlu ọba níbikíbi tí ó bá ń lọ. Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ wọnú ilé Ọlọrun, pípa ni kí ẹ pa á.” Àwọn ọmọ Lefi ati gbogbo ọmọ Juda ṣe gẹ́gẹ́ bí Jehoiada alufaa ti pàṣẹ fún wọn. Olukuluku kó àwọn eniyan rẹ̀ tí wọ́n ṣíwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi wá, wọ́n dúró pẹlu àwọn tí wọ́n fẹ́ gba ipò wọn, nítorí Jehoiada alufaa kò jẹ́ kí wọ́n túká. Jehoiada fún àwọn ọ̀gágun ní ọ̀kọ̀ ati apata Dafidi tí wọ́n ti kó pamọ́ sinu ilé Ọlọrun. Ó ní kí àwọn eniyan náà dúró, kí wọn máa ṣọ́ ọba, olukuluku pẹlu ohun ìjà lọ́wọ́. Wọ́n tò láti ìhà gúsù ilé náà títí dé ìhà àríwá, ati ní àyíká pẹpẹ ati ti ilé náà. Jehoiada bá mú Joaṣi jáde, ó gbé adé lé e lórí, ó fún un ní ìwé òfin. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe fi Joaṣi jọba, Jehoiada alufaa ati àwọn ọmọ rẹ̀ sì fi àmì òróró yàn án lọ́ba. Gbogbo eniyan hó pé, “Kí ọba pẹ́.” Nígbà tí Atalaya gbọ́ híhó àwọn eniyan, ati bí wọ́n ti ń sá kiri tí wọ́n sì ń yin ọba, ó lọ sí ilé OLUWA níbi tí àwọn eniyan péjọ sí, ó rí i tí ọba náà dúró lẹ́bàá òpó lẹ́nu ọ̀nà, àwọn ọ̀gágun ati àwọn tí wọn ń fọn fèrè dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Gbogbo eniyan ń hó ìhó ayọ̀, wọ́n ń fọn fèrè, àwọn tí ń lo ohun èlò orin ń fi wọ́n kọrin, àwọn eniyan sì ń gberin. Nígbà tí Atalaya rí nǹkan tí ń ṣẹlẹ̀, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ẹ̀rù bà á, ó sì kígbe lóhùn rara pé, “Ọ̀tẹ̀ nìyí! Ọ̀tẹ̀ nìyí!” Jehoiada bá rán àwọn ọ̀gágun ọmọ ogun ọgọrun-un pé, “Ẹ fà á síta láàrin àwọn ọmọ ogun, ẹni tí ó bá tẹ̀lé e, ẹ pa á.” Nítorí àwọn alufaa ní kí wọ́n má pa á ninu tẹmpili OLUWA. Wọ́n bá mú un lọ sí ẹnu ọ̀nà Ẹṣin, ní ààfin, wọ́n sì pa á sibẹ. Jehoiada bá àwọn eniyan náà dá majẹmu pẹlu ọba, pé ti OLUWA ni àwọn yóo máa ṣe. Lẹ́yìn náà, gbogbo wọn lọ sí ilé oriṣa Baali, wọ́n wó o palẹ̀, wọ́n wó pẹpẹ ati àwọn ère túútúú, wọ́n sì pa Matani, tí ó jẹ́ alufaa Baali, níwájú pẹpẹ. Jehoiada yan àwọn aṣọ́nà fún ilé OLUWA, lábẹ́ àkóso àwọn alufaa, ọmọ Lefi, ati àwọn ọmọ Lefi tí Dafidi ti ṣètò láti máa rú ẹbọ sísun sí OLUWA bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin Mose, pẹlu àjọyọ̀ ati orin, gẹ́gẹ́ bí Dafidi ti ṣètò. Ó fi àwọn aṣọ́nà sí ẹnu àwọn ọ̀nà ilé OLUWA kí ẹnikẹ́ni tí kò bá mọ́ má baà wọlé. Òun pẹlu àwọn balogun, àwọn eniyan jàǹkànjàǹkàn, àwọn gomina, ati gbogbo eniyan ilẹ̀ náà mú ọba láti ilé OLUWA, wọ́n gba ẹnu ọ̀nà òkè wá sí ààfin, wọ́n sì fi í jókòó lórí ìtẹ́. Inú gbogbo àwọn eniyan dùn, ìlú sì rọ̀ wọ̀ọ̀, nítorí pé wọ́n ti pa Atalaya. Ọmọ ọdún meje ni Joaṣi nígbà tí ó gorí oyè, ó sì jọba ní Jerusalẹmu fún ogoji ọdún. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Sibaya, ará Beeriṣeba. Joaṣi ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA ní gbogbo ọjọ́ ayé Jehoiada alufaa. Jehoiada fẹ́ iyawo meji fún un, wọ́n sì bímọ fún un lọkunrin ati lobinrin. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Joaṣi pinnu láti tún ilé OLUWA ṣe. Ó pe gbogbo àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi jọ, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí àwọn ìlú Juda, kí ẹ máa gba owó lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọmọ Israẹli láti máa fi tún ilé OLUWA Ọlọrun yín ṣe ní ọdọọdún. Ẹ mójútó iṣẹ́ náà kí ẹ sì ṣe é kíákíá.” Ṣugbọn àwọn alufaa kò tètè lọ. Nítorí náà, ọba ranṣẹ pe Jehoiada tí ó jẹ́ olórí wọn, ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ló dé tí ẹ kò fi jẹ́ kí àwọn ọmọ Lefi lọ máa gba owó fún àgọ́ ẹ̀rí lọ́wọ́ àwọn eniyan Juda ati Jerusalẹmu bí Mose, iranṣẹ OLUWA, ti pa á láṣẹ?” (Nítorí pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Atalaya, obinrin burúkú n nì, ti fọ́ ilé Ọlọrun, wọ́n sì ti kó gbogbo ohun èlò mímọ́ ibẹ̀, wọ́n ti lò ó fún oriṣa Baali.) Nítorí náà, ọba pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe àpótí kan tí àwọn eniyan yóo máa sọ owó sí, kí wọ́n sì gbé e sí ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA. Wọ́n kéde káàkiri Jerusalẹmu ati Juda pé kí wọ́n máa mú owó orí wá fún OLUWA gẹ́gẹ́ bí Mose iranṣẹ Ọlọrun ti pàṣẹ fún Israẹli ninu aṣálẹ̀. Gbogbo àwọn ìjòyè ati gbogbo eniyan fi tayọ̀tayọ̀ mú owó orí wọn wá, wọ́n ń sọ ọ́ sinu àpótí náà títí tí ó fi kún. Nígbà tí àwọn Lefi bá gbé àpótí náà wá fún àwọn òṣìṣẹ́ ọba, tí wọ́n sì rí i pé owó pọ̀ ninu rẹ̀, akọ̀wé ọba ati aṣojú olórí alufaa yóo da owó kúrò ninu àpótí, wọn yóo sì gbé e pada sí ààyè rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe ní ojoojumọ, wọ́n sì rí ọpọlọpọ owó kó jọ. Ọba ati Jehoiada gbé owó náà fún àwọn tí wọn ń ṣe àkóso iṣẹ́ ilé OLUWA, wọ́n gba àwọn ọ̀mọ̀lé, àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà ati àwọn alágbẹ̀dẹ irin ati ti bàbà, láti tún ilé OLUWA ṣe. Gbogbo àwọn tí wọ́n kópa ninu iṣẹ́ náà fi tagbára tagbára ṣe é. Iṣẹ́ náà tẹ̀síwájú títí tí wọ́n fi tún ilé OLUWA náà ṣe tán, tí ó sì rí bíi ti iṣaaju tí ó sì tún lágbára sí i. Nígbà tí wọ́n tún ilé OLUWA náà ṣe tán, wọ́n kó owó tí ó kù pada sọ́dọ̀ ọba ati Jehoiada. Wọ́n fi owó náà ṣe àwọn ohun èlò fún ìsìn ati ẹbọ sísun ní ilé OLUWA, ati àwo fún turari ati ohun èlò wúrà ati fadaka. Wọ́n sì ń rú ẹbọ sísun ní ilé OLUWA lojoojumọ, ní gbogbo àkókò Jehoiada. Nígbà tí Jehoiada dàgbà tí ó di arúgbó, ó kú nígbà tí ó pé ẹni aadoje (130) ọdún. Wọ́n sin ín sí ibojì àwọn ọba ní ìlú Dafidi nítorí iṣẹ́ rere tí ó ṣe ní Israẹli fún Ọlọrun ati ní ilé mímọ́ rẹ̀. Ṣugbọn nígbà tí Jehoiada kú, àwọn ìjòyè ní Juda wá kí ọba, wọ́n sì júbà rẹ̀, ó sì gba ìmọ̀ràn wọn. Wọ́n kọ ilé OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn sílẹ̀, wọ́n sì ń sin oriṣa Aṣera ati àwọn ère mìíràn. Nítorí ìwà burúkú yìí, inú bí OLUWA sí Juda ati Jerusalẹmu. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA rán àwọn wolii sí wọn láti darí wọn pada sọ́dọ̀ rẹ̀, tí wọ́n sì ń kìlọ̀ fún wọn, wọ́n kọ etí dídi sí àwọn wolii. Nígbà tí ó yá, Ẹ̀mí Ọlọrun bà lé Sakaraya, ọmọ Jehoiada alufaa, ó bá dìde dúró láàrin àwọn eniyan, ó ní, “Ọlọrun ń bèèrè pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi tàpá sí òfin òun OLUWA; ṣé ẹ kò fẹ́ kí ó dára fun yín ni? Nítorí pé, ẹ ti kọ OLUWA sílẹ̀, òun náà sì ti kọ̀ yín sílẹ̀.’ ” Ṣugbọn wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọn. Lẹ́yìn náà, ọba pàṣẹ pé kí wọn sọ ọ́ lókùúta pa ninu gbọ̀ngàn ilé OLUWA. Joaṣi ọba kò ranti oore tí Jehoiada, baba Sakaraya ṣe fún un, ṣugbọn ó pa ọmọ rẹ̀. Nígbà tí ó sì ń kú lọ, ó ní, “Kí OLUWA wo ohun tí o ṣe yìí, kí ó sì gbẹ̀san.” Bí ọdún náà ti ń dópin lọ, àwọn ọmọ ogun Siria gbógun ti Joaṣi. Nígbà tí wọ́n dé Juda ati Jerusalẹmu, wọ́n pa gbogbo àwọn ìjòyè wọn, wọ́n sì kó gbogbo ìkógun wọn ranṣẹ sí Damasku. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé díẹ̀ ni àwọn ọmọ ogun Siria tí wọ́n wá, sibẹsibẹ OLUWA fi ọpọlọpọ ninu àwọn ọmọ ogun Juda lé wọn lọ́wọ́ nítorí pé wọ́n ti kọ OLUWA Ọlọrun baba wọn sílẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ìdájọ́ Joaṣi ọba. Ọba fara gbọgbẹ́ ninu ogun náà, nígbà tí àwọn ogun Siria sì lọ tán, àwọn balogun rẹ̀ dìtẹ̀ mọ́ ọn nítorí pé ó pa ọmọ Jehoiada alufaa, wọ́n sì pa á lórí ibùsùn rẹ̀. Wọ́n sin ín sí ìlú Dafidi, ṣugbọn kì í ṣe inú ibojì àwọn ọba. Àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọba ni Sabadi, ọmọ Ṣimeati ará Amoni, ati Jehosabadi ọmọ Ṣimiriti ará Moabu. Ìtàn àwọn ọmọ rẹ̀, ati ọpọlọpọ àsọtẹ́lẹ̀ tí a sọ nípa rẹ̀, ati bí ó ti tún ilé Ọlọrun ṣe wà, tí a kọ ọ́ sinu ìwé Ìtàn Àwọn Ọba. Amasaya ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni Amasaya nígbà tí ó jọba; ó sì wà lórí oyè fún ọdún mọkandinlọgbọn ní Jerusalẹmu. Ìyá rẹ̀ ni Jehoadini ará Jerusalẹmu. Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA, ṣugbọn kò fi tọkàntọkàn sìn ín. Lẹ́yìn ìgbà tí ìjọba rẹ̀ ti fẹsẹ̀ múlẹ̀, ó pa gbogbo àwọn tí wọ́n pa baba rẹ̀. Ṣugbọn kò pa àwọn ọmọ wọn, gẹ́gẹ́ bí ìwé òfin Mose ti wí, níbi tí OLUWA ti pàṣẹ, pé, “A kò gbọdọ̀ pa baba nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọmọ, tabi kí á pa ọmọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ baba; olukuluku ni yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀.” Amasaya pe àwọn eniyan Juda ati Bẹnjamini jọ, ó pín wọn sábẹ́ àwọn ọ̀gágun ní ẹgbẹẹgbẹrun ati ọgọọgọrun-un gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn. Àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún ati jù bẹ́ẹ̀ lọ ni gbogbo àwọn tí ó kó jọ. Gbogbo wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹẹdogun (300,000) akọni ọkunrin tí wọ́n tó lọ sójú ogun, tí wọ́n sì lè lo ọ̀kọ̀ ati apata. Ó tún fi ọgọrun-un ìwọ̀n talẹnti fadaka lọ bẹ ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) akọni lọ́wẹ̀ ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli. Ṣugbọn wolii Ọlọrun kan lọ bá Amasaya, ó sọ fún un pé, “Kabiyesi, má jẹ́ kí àwọn ọmọ ogun Israẹli bá ọ lọ, nítorí OLUWA kò ní wà pẹlu Israẹli ati àwọn ará Efuraimu wọnyi. Ṣugbọn bí o bá wá rò pé àwọn wọnyi ni yóo jẹ́ kí ogun rẹ lágbára, OLUWA yóo bì ọ́ ṣubú níwájú àwọn ọ̀tá rẹ. Nítorí Ọlọrun lágbára láti ranni lọ́wọ́ ati láti bini ṣubú.” Amasaya bèèrè lọ́wọ́ wolii náà pé, “Kí ni kí á ṣe nípa ọgọrun-un talẹnti tí mo ti fún àwọn ọmọ ogun Israẹli?” Ó dáhùn pé, “OLUWA lè fún ọ ní ohun tí ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.” Nítorí náà Amasaya dá àwọn ọmọ ogun Efuraimu tí ó gbà pada sílé wọn. Nítorí náà, inú bí wọn gan-an sí Juda, wọ́n sì pada sílé pẹlu ìrúnú. Ṣugbọn Amasaya fi ìgboyà kó ogun rẹ̀ lọ sí Àfonífojì Iyọ̀, ó sì pa ẹgbaarun (10,000) ninu àwọn ọmọ ogun Seiri. Wọ́n mú ẹgbaarun (10,000) mìíràn láàyè, wọ́n kó wọn lọ sí góńgó orí òkè kan, wọ́n jù wọ́n sí ìsàlẹ̀, gbogbo wọn sì ṣègbé. Àwọn ọmọ ogun Israẹli tí Amasaya dá pada, tí kò jẹ́ kí wọ́n tẹ̀lé òun lọ sógun bá lọ, wọ́n kọlu àwọn ìlú Juda láti Samaria títí dé Beti Horoni. Wọ́n pa ẹgbẹẹdogun (3,000) eniyan, wọ́n sì kó ọpọlọpọ ìkógun. Amasaya kó oriṣa àwọn ará Edomu tí ó ṣẹgun wá sílé. Ó kó wọn kalẹ̀, ó ń bọ wọ́n, ó sì ń rúbọ sí wọn. Inú bí OLUWA sí Amasaya gan-an, ó sì rán wolii kan sí i kí ó sọ fún un pé, “Kí ló dé tí o fi ń bọ àwọn oriṣa tí kò lè gba àwọn eniyan rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ?” Bí wolii yìí ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni ọba dá a lóhùn pé, “Panumọ́, ṣé wọ́n fi ọ́ ṣe olùdámọ̀ràn ọba ni? Àbí o fẹ́ kú ni.” Wolii náà bá dákẹ́, ṣugbọn, kí ó tó dákẹ́ ó ní, “Mo mọ̀ pé Ọlọrun ti pinnu láti pa ọ́ run fún ohun tí o ṣe yìí, ati pé, o kò tún fetí sí ìmọ̀ràn mi.” Lẹ́yìn tí Amasaya, ọba Juda, ṣe àpérò pẹlu àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀, ó ranṣẹ sí Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi, ọmọ Jehu, ọba Israẹli pé, “Wá, jẹ́ kí á kojú ara wa.” Jehoaṣi ọba Israẹli ranṣẹ sí ọba Juda pé, “Ní àkókò kan, ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n kan ní Lẹbanoni ranṣẹ sí igi kedari ní Lẹbanoni pé, ‘Mo fẹ́ fẹ́ ọmọbinrin rẹ fún ọmọkunrin mi.’ Ẹranko ìgbẹ́ kan ń kọjá lọ, ó sì tẹ ẹ̀gún náà mọ́lẹ̀. O bẹ̀rẹ̀ sí fọ́nnu pẹlu ìgbéraga pé o ti ṣẹgun àwọn ará Edomu, ṣugbọn, mo gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn pé kí o dúró jẹ́ẹ́ sí ilé rẹ. Kí ló dé tí ò ń fi ọwọ́ ara rẹ fa ìjàngbọ̀n tí ó lè fa ìṣubú ìwọ ati àwọn eniyan rẹ?” Ṣugbọn Amasaya kọ̀, kò gbọ́, nítorí pé Ọlọrun ni ó mú kí ọkàn rẹ̀ le, kí Ọlọrun lè fi Juda lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́ nítorí pé wọ́n ń bọ àwọn oriṣa Edomu. Nítorí náà, Jehoaṣi, ọba Israẹli, gòkè lọ, òun ati Amasaya ọba Juda sì kojú ara wọn lójú ogun ní Beti Ṣemeṣi ní ilẹ̀ Juda. Àwọn ará Israẹli ṣẹgun àwọn ará Juda, olukuluku sì fọ́nká lọ sí ilé rẹ̀. Jehoaṣi, ọba Israẹli mú Amasaya, ọba Juda, ọmọ Joaṣi, ọmọ Ahasaya, ní ojú ogun, ní Beti Ṣemeṣi; ó sì mú un wá sí Jerusalẹmu. Ó wó odi Jerusalẹmu palẹ̀ láti Ẹnubodè Efuraimu títí dé Ẹnubodè Kọ̀rọ̀. Gígùn ibi tí à ń wí yìí jẹ́ irinwo igbọnwọ (200 mita.) Ó kó gbogbo wúrà, fadaka ati àwọn ohun èlò tí ó wà lábẹ́ ìtọ́jú Obedi Edomu ní ilé Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ààfin ọba, ó kó gbogbo ìṣúra tí ó wà níbẹ̀ ati àwọn eniyan, ó sì pada sí Samaria. Amasaya, ọmọ Joaṣi, ọba Juda gbé ọdún mẹẹdogun lẹ́yìn ikú Jehoaṣi, ọmọ Jehoahasi, ọba Israẹli. Àkọsílẹ̀ àwọn nǹkan yòókù tí Amasaya ṣe, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, wà ninu ìwé àwọn ọba Juda ati Israẹli. Láti ìgbà tí Amasaya ti pada lẹ́yìn OLUWA ni àwọn eniyan ti dìtẹ̀ mọ́ ọn ní Jerusalẹmu, nítorí náà, ó sá lọ sí Lakiṣi. Ṣugbọn wọ́n lépa rẹ̀ lọ sí Lakiṣi, wọ́n sì pa á níbẹ̀. Wọ́n fi ẹṣin gbé òkú rẹ̀ wá sí Jerusalẹmu, wọ́n sì sin ín sí ìlú Dafidi ní ibojì àwọn baba rẹ̀. Gbogbo àwọn ará Juda fi Usaya, ọmọ ọdún mẹrindinlogun jọba lẹ́yìn ikú Amasaya baba rẹ̀. Ó tún Eloti kọ́, ó gbà á pada fún Juda lẹ́yìn ikú Amasaya, baba rẹ̀. Ọmọ ọdún mẹrindinlogun ni Usaya nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mejilelaadọta. Jekolaya, ará Jerusalẹmu ni ìyá rẹ̀. Ó ṣe nǹkan tí ó tọ́ níwájú OLUWA, bí Amasaya baba rẹ̀. Ó sin Ọlọrun nígbà ayé Sakaraya, nítorí pé Sakaraya ń kọ́ ọ ní ìbẹ̀rù Ọlọrun. Ní gbogbo àkókò tí ó fi ń sin Ọlọrun, Ọlọrun bukun un. Ó gbógun ti àwọn ará Filistia, ó sì wó odi Gati, ati ti Jabine ati ti Aṣidodu lulẹ̀. Ó kọ́ àwọn ìlú olódi ní agbègbè Aṣidodu ati ní ibòmíràn ní ilẹ̀ àwọn ará Filistia. Ọlọrun ràn án lọ́wọ́, ó ṣẹgun àwọn ará Filistia ati àwọn ará Arabia tí wọ́n ń gbé Guribaali ati àwọn ará Meuni. Àwọn ará Amoni ń san ìṣákọ́lẹ̀ fún Usaya, òkìkí rẹ̀ kàn káàkiri títí dé agbègbè ilẹ̀ Ijipti, nítorí pé ó di alágbára gan-an. Usaya tún kọ́ àwọn ilé ìṣọ́ ní Jerusalẹmu níbi Ẹnubodè tí ó wà ní igun odi, ati sí ibi Ẹnubodè àfonífojì, ati níbi Ìṣẹ́po Odi. Ó sì mọ odi sí wọn. Ó tún kọ́ àwọn ilé ìṣọ́ sinu aṣálẹ̀, ó gbẹ́ ọpọlọpọ kànga, nítorí pé ó ní ọpọlọpọ agbo ẹran ọ̀sìn ní àwọn ẹsẹ̀ òkè ati ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. Ó ní àwọn òṣìṣẹ́ tí wọn ń dá oko fún un ati àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́ ninu àjàrà, lórí òkè ati lórí àwọn ilẹ̀ ọlọ́ràá, nítorí ó fẹ́ràn iṣẹ́ àgbẹ̀. Usaya ní ọpọlọpọ ọmọ ogun, tí wọ́n tó ogun lọ, ó pín wọn ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí gẹ́gẹ́ bí ètò tí Jeieli akọ̀wé, ati Maaseaya, ọ̀gágun ṣe, lábẹ́ àkóso Hananaya, ọ̀kan ninu àwọn ọ̀gágun ọba. Gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ baálé, tí wọ́n sì jẹ́ akọni ọkunrin jẹ́ ẹgbẹtala (2,600). Àwọn ọmọ ogun tí wọ́n wà lábẹ́ wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹẹdogun ó lé ẹẹdẹgbaarin ati ẹẹdẹgbaata (307,500), wọ́n lágbára láti jagun, ati láti bá ọba dojú kọ àwọn ọ̀tá rẹ̀. Usaya ọba fún gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ní apata, ọ̀kọ̀, àṣíborí, ẹ̀wù ihamọra, ọfà, ati òkúta fún kànnàkànnà wọn. Ó ní àwọn ẹ̀rọ tí àwọn alágbẹ̀dẹ ṣe sórí àwọn ilé ìṣọ́ ati àwọn igun odi ní Jerusalẹmu láti máa tafà ati láti máa sọ àwọn òkúta ńláńlá. Òkìkí rẹ̀ sì kàn káàkiri nítorí pé Ọlọrun ràn án lọ́wọ́ ní ọ̀nà ìyanu títí ó fi di alágbára. Ṣugbọn nígbà tí Usaya di alágbára tán, ìgbéraga rẹ̀ tì í ṣubú. Ó ṣe aiṣootọ sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀. Ó wọ inú tẹmpili OLUWA, ó lọ sun turari lórí pẹpẹ turari. Ṣugbọn Asaraya, alufaa, wọlé lọ bá a pẹlu àwọn ọgọrin alufaa tí wọ́n jẹ́ akọni. Wọ́n dojú kọ ọ́, wọ́n ní, “Usaya, kò tọ́ fún ọ láti sun turari sí OLUWA; iṣẹ́ àwọn alufaa tí wọ́n jẹ́ ọmọ Aaroni ni, àwọn tí a ti yà sọ́tọ̀ láti máa sun turari. Jáde kúrò ninu ibi mímọ́! Nítorí o ti ṣe ohun tí kò tọ́, kò sì buyì kún ọ lọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun rẹ.” Inú bí Usaya nítorí pé àwo turari ti wà lọ́wọ́ rẹ̀ tí ó fẹ́ fi sun turari. Níbi tí ó ti ń bínú sí àwọn alufaa, àrùn ẹ̀tẹ̀ yọ níwájú rẹ̀, lójú àwọn alufaa ninu ilé OLUWA. Nígbà tí Asaraya, olórí alufaa ati àwọn alufaa rí i tí ẹ̀tẹ̀ yọ níwájú rẹ̀, wọ́n yára tì í jáde. Ìkánjú ni òun pàápàá tilẹ̀ bá jáde, nítorí pé OLUWA ti jẹ ẹ́ níyà. Usaya ọba di adẹ́tẹ̀ títí ọjọ́ ikú rẹ̀. Ọ̀tọ̀ ni wọ́n kọ́ ilé fún un tí ó ń dá gbé; nítorí wọ́n yọ ọ́ kúrò ninu ilé OLUWA. Jotamu ọmọ rẹ̀ di alákòóso ìjọba, ó sì ń darí àwọn ará ìlú. Àwọn nǹkan yòókù tí Usaya ṣe, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, wà ninu àkọsílẹ̀ wolii Aisaya, ọmọ Amosi. Nígbà tí Usaya kú, wọ́n sin ín sí itẹ́ àwọn ọba, wọn kò sin ín sinu ibojì àwọn ọba, nítorí wọ́n ní, “Adẹ́tẹ̀ ni.” Jotamu ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni Jotamu nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹrindinlogun. Jeruṣa, ọmọ Sadoku ni ìyá rẹ̀. Ó ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA, gẹ́gẹ́ bíi Usaya, baba rẹ̀; àfi pé òun kò lọ sun turari ninu tẹmpili OLUWA. Ṣugbọn àwọn eniyan ń bá ìwà burúkú wọn lọ. Ó kọ́ ẹnu ọ̀nà òkè ilé OLUWA, ó sì tún ògiri Ofeli mọ. Ó kọ́ àwọn ìlú ní agbègbè olókè Juda ó sì kọ́ ibi ààbò ati ilé-ìṣọ́ ninu igbó lára òkè. Ó bá ọba àwọn ará Amoni jà, ó sì ṣẹgun wọn. Ní ọdún tí ó ṣẹgun wọn, wọ́n fún un ní ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ẹgbaarun (10,000) ìwọ̀n kori alikama ati ẹgbaarun (10,000) ìwọ̀n kori ọkà baali. Iye kan náà ni wọ́n fún un ní ọdún keji ati ọdún kẹta. Jotamu di alágbára nítorí ó rìn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ níwájú OLUWA Ọlọrun rẹ̀. Gbogbo nǹkan yòókù tí Jotamu ṣe ati àwọn ogun tí ó jà, ati àwọn nǹkan mìíràn tí ó tún ṣe ni a kọ sinu ìwé àwọn ọba Israẹli ati ti Juda. Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mẹrindinlogun ní Jerusalẹmu. Nígbà tí Jotamu kú, wọ́n sin ín ní ìlú Dafidi, Ahasi ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Ẹni ogún ọdún ni Ahasi nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mẹrindinlogun ní Jerusalẹmu. Kò sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA bíi Dafidi baba ńlá rẹ̀. Ṣugbọn ó ṣe bí àwọn ọba Israẹli, ó tilẹ̀ yá ère fún oriṣa Baali. Ó ń sun turari ní àfonífojì àwọn ọmọ Hinomu, ó sì ń fi àwọn ọmọkunrin rẹ̀ rú ẹbọ sísun, gẹ́gẹ́ bí ìwà ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA lé jáde kúrò níwájú Israẹli ń hù. Ó rúbọ, ó sun turari ní àwọn ibi ìrúbọ, ati lórí òkè káàkiri ati lábẹ́ gbogbo igi tútù. Nítorí náà OLUWA Ọlọrun rẹ̀ fi í lé ọba Siria lọ́wọ́. Ọba Siria ṣẹgun rẹ̀, ó sì kó àwọn eniyan rẹ̀ lẹ́rú lọ sí Damasku. Ọlọrun tún fi lé ọba Israẹli lọ́wọ́, ó ṣẹgun rẹ̀, ó sì pa àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ní ìpakúpa. Ní ọjọ́ kan ṣoṣo, Peka, ọmọ Remalaya, ọba Israẹli, pa ọ̀kẹ́ mẹfa (120,000) ninu àwọn ọmọ ogun Juda; tí gbogbo wọn sì jẹ́ akọni. Ọlọrun jẹ́ kí àwọn nǹkan wọnyi ṣẹlẹ̀ sí wọn nítorí pé wọ́n ti kọ OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn sílẹ̀. Sikiri, akikanju jagunjagun kan, ará Efuraimu pa Maaseaya, ọmọ ọba, ati Asirikamu, olórí ogun tí ń ṣọ́ ààfin ọba, ati Elikana, igbákejì ọba. Àwọn tí ará ilẹ̀ Israẹli dè ní ìgbèkùn lọ ninu àwọn ará ilé Juda jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000) àtàwọn obinrin, àtàwọn ọmọkunrin, àtàwọn ọmọbinrin; wọ́n sì kó ọpọlọpọ ìkógun lọ sí Samaria. Wolii OLUWA kan tí ń jẹ́ Odedi wà ní ìlú Samaria; ó lọ pàdé àwọn ọmọ ogun Israẹli nígbà tí wọ́n ń pada bọ̀. Ó wí fún wọn pé, “Nítorí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín bínú sí àwọn ará Juda ni ó fi jẹ́ kí ẹ ṣẹgun wọn, ṣugbọn ẹ pa wọ́n ní ìpakúpa tóbẹ́ẹ̀ tí Ọlọrun pàápàá ṣàkíyèsí rẹ̀. Ẹ tún wá fẹ́ kó tọkunrin tobinrin Juda ati Jerusalẹmu lẹ́rú. Ṣé ẹ̀yin alára náà kò ti dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun yín? Ẹ gbọ́ tèmi, ẹ dá àwọn arakunrin yín tí ẹ ti kó lẹ́rú pada, nítorí ibinu OLUWA wà lórí yín.” Nígbà náà ni àwọn ìjòyè kan lára àwọn ará Efuraimu: Asaraya, ọmọ Johanani, Berekaya, ọmọ Meṣilemoti, Jehisikaya, ọmọ Ṣalumu ati Amasa, ọmọ Hadilai dìde, wọ́n tako àwọn tí ń ti ojú ogun bọ̀, wọ́n sọ fún wọn pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ kó àwọn ìgbèkùn wọnyi wọ ibí wá, kí ẹ tún wá dákún ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹ̀bi tí ó wà lọ́rùn wa tẹ́lẹ̀. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa pọ̀ tẹ́lẹ̀, ọwọ́ ibinu OLUWA sì ti wà lára Israẹli.” Nítorí náà, àwọn ọmọ ogun náà dá àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú ati ẹrù tí wọn ń kó bọ̀ sílẹ̀ níwájú àwọn ìjòyè ati gbogbo ìjọ eniyan Israẹli. Àwọn kan tí wọ́n yàn bá dìde, wọ́n kó àwọn tí àwọn ọmọ ogun kó lẹ́rú ati ẹrù wọn, wọ́n wọ àwọn tí wọ́n wà ní ìhòòhò láṣọ; wọ́n fún wọn ní bàtà, wọ́n pèsè oúnjẹ ati nǹkan mímu fún wọn, wọ́n sì fi òróró sí ọgbẹ́ wọn. Wọ́n gbé gbogbo àwọn tí àárẹ̀ ti mú gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arakunrin wọn ní Jẹriko, ìlú ọlọ́pẹ. Lẹ́yìn náà wọ́n pada lọ sí Samaria. Ní àkókò yìí, Ahasi ranṣẹ lọ bẹ ọba Asiria lọ́wẹ̀, nítorí pé àwọn ará Edomu tún pada wá gbógun ti Juda; wọ́n ṣẹgun wọn, wọ́n sì kó àwọn kan ninu wọn lẹ́rú lọ. Àwọn ará Filistia ti gbógun ti àwọn ìlú tí ó wà ní ẹsẹ̀ òkè, ati ní agbègbè Nẹgẹbu, ní Juda. Wọ́n jagun gba Beti Ṣemeṣi, Aijaloni, ati Gederotu, wọ́n sì gba Soko, Timna, ati Gimso pẹlu àwọn ìletò ìgbèríko wọn, wọ́n bá ń gbé ibẹ̀. OLUWA rẹ Juda sílẹ̀ nítorí Ahasi, ọba Juda, nítorí pé ó hùwà ìríra ní Juda, ó sì ṣe aiṣootọ sí OLUWA. Nítorí náà Tigilati Pileseri, ọba Asiria gbógun ti Ahasi, ó sì fìyà jẹ ẹ́, dípò kí ó ràn án lọ́wọ́. Ahasi kó ohun ìṣúra inú ilé OLUWA, ati ti ààfin, ati ti inú ilé àwọn ìjòyè, ó fi san ìṣákọ́lẹ̀ fún ọba Asiria, sibẹsibẹ ọba Asiria kò ràn án lọ́wọ́. Ní àkókò ìyọnu Ahasi ọba, ó túbọ̀ ṣe alaiṣootọ sí OLUWA ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. Ó rúbọ sí àwọn oriṣa àwọn ará Damasku tí wọ́n ṣẹgun rẹ̀, nítorí ó rò ninu ara rẹ̀ pé, “Àwọn oriṣa àwọn ọba Siria ràn wọ́n lọ́wọ́, n óo rúbọ sí wọn kí wọ́n lè ran èmi náà lọ́wọ́.” Ṣugbọn àwọn oriṣa ọ̀hún ni wọ́n fa ìparun bá òun ati orílẹ̀-èdè rẹ̀. Gbogbo ohun èlò ilé Ọlọrun ni Ahasi gé wẹ́wẹ́, ó sì ti ìlẹ̀kùn ibẹ̀; ó wá tẹ́ pẹpẹ oriṣa káàkiri Jerusalẹmu. Ó ṣe ibi ìrúbọ káàkiri àwọn ìlú Juda níbi tí yóo ti máa sun turari sí àwọn oriṣa. Nípa bẹ́ẹ̀, ó mú OLUWA Ọlọrun àwọn baba rẹ̀ bínú. Àkọsílẹ̀ gbogbo nǹkan yòókù tí Ahasi ṣe, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, wà ninu ìwé ìtàn àwọn ọba Juda ati ti Israẹli. Nígbà tí Ahasi ọba kú, wọ́n sin ín sí Jerusalẹmu, wọn kò sì sin ín sinu ibojì àwọn ọba. Hesekaya ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Hesekaya jọba ní Juda nígbà tí ó di ẹni ọdún mẹẹdọgbọn; ó sì wà lórí oyè fún ọdún mọkandinlọgbọn. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Abija, ọmọ Sakaraya. Ó ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA, gẹ́gẹ́ bí Dafidi baba ńlá rẹ̀ ti ṣe. Ní oṣù kinni ọdún kinni ìjọba rẹ̀, ó ṣí àwọn ìlẹ̀kùn ilé OLUWA, ó sì tún wọn ṣe. Ó kó àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi jọ sí gbàgede tí ó wà ní apá ìlà oòrùn ilé Ọlọrun. Ó ní, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Lefi, ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì ya ilé OLUWA, Ọlọrun àwọn baba yín sí mímọ́ pẹlu. Ẹ kó gbogbo àwọn nǹkan ẹ̀gbin kúrò ninu ibi mímọ́, nítorí àwọn baba wa ti ṣe aiṣododo, wọ́n sì ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, Ọlọrun wa. Wọ́n kọ OLUWA sílẹ̀, wọ́n gbójú kúrò lára ibùgbé rẹ̀, wọ́n sì kẹ̀yìn sí i. Wọ́n ti ìlẹ̀kùn yàrá àbáwọlé tẹmpili, wọ́n pa fìtílà tí ó wà ní ibi mímọ́, wọn kò sun turari, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò rú ẹbọ sísun ní ibi mímọ́ sí Ọlọrun Israẹli. Nítorí náà ni OLUWA ṣe bínú sí Juda ati Jerusalẹmu, ohun tí Ọlọrun fi wọ́n ṣe sì dẹ́rùba gbogbo eniyan. Wọ́n di ẹni ẹ̀gàn ati ẹni àrípòṣé, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti rí i lónìí. Ìdí nìyí tí àwọn baba wa fi ṣubú lójú ogun tí wọ́n sì kó àwọn ọmọ ati àwọn aya wa lẹ́rú. “Nisinsinyii, mo ti pinnu láti bá OLUWA Ọlọrun Israẹli dá majẹmu, kí ibinu gbígbóná rẹ̀ lè kúrò lórí wa. Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má jáfara, nítorí pé OLUWA ti yàn yín láti dúró níwájú rẹ̀, ati láti sìn ín; láti jẹ́ iranṣẹ rẹ̀ ati láti máa sun turari sí i.” Àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ṣíṣe ní tẹmpili nìwọ̀nyí: láti inú ìdílé Kohati: Mahati, ọmọ Amasai, ati Joẹli, ọmọ Asaraya; láti inú ìdílé Merari: Kiṣi, ọmọ Abidi ati Asaraya, ọmọ Jahaleleli; láti inú ìdílé Geriṣoni: Joa, ọmọ Sima ati Edẹni, ọmọ Joa. Láti inú ìdílé Elisafani: Ṣimiri ati Jeueli; láti inú ìdílé Asafu: Sakaraya ati Matanaya, láti inú ìdílé Hemani: Jeueli ati Ṣimei; láti inú ìdílé Jedutuni: Ṣemaaya ati Usieli. Wọ́n bá kó àwọn arakunrin wọn jọ, wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́. Wọ́n wọ ilé OLUWA láti tọ́jú rẹ̀ bí ọba ti pa á láṣẹ, gẹ́gẹ́ bí òfin OLUWA. Àwọn alufaa wọ ibi mímọ́ lọ láti tọ́jú rẹ̀. Gbogbo ohun aláìmọ́ tí wọ́n rí ninu tẹmpili OLUWA ni wọ́n kó sí àgbàlá ilé náà. Àwọn ọmọ Lefi sì kó gbogbo wọn lọ dà sí odò Kidironi lẹ́yìn ìlú. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ya ara wọn sí mímọ́ ní ọjọ́ kinni oṣù kinni. Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹjọ, wọ́n wá sí yàrá àbáwọlé ilé OLUWA. Ọjọ́ mẹjọ ni wọ́n fi ya ilé OLUWA sí mímọ́, wọ́n parí ní ọjọ́ kẹrindinlogun oṣù náà. Lẹ́yìn náà, wọ́n tọ Hesekaya ọba lọ, wọ́n sọ fún un pé, “A ti tọ́jú ilé OLUWA: ati pẹpẹ ẹbọ sísun, ati gbogbo ohun èlò rẹ̀, ati tabili àkàrà ìfihàn ati gbogbo ohun èlò rẹ̀. Gbogbo àwọn ohun èlò tí Ahasi ọba ti patì nígbà tí ó ṣe aiṣododo ni a ti tọ́jú, tí a sì ti yà sí mímọ́. A ti kó gbogbo wọn siwaju pẹpẹ OLUWA.” Hesekaya ọba dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, ó kó gbogbo àwọn ìjòyè ìlú jọ, wọ́n bá lọ sinu ilé OLUWA. Wọ́n fi akọ mààlúù meje, àgbò meje, ọ̀dọ́ aguntan meje ati òbúkọ meje rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ìjọba Hesekaya, ati ilé OLUWA ati ilé Juda. Ọba pàṣẹ pé kí àwọn alufaa, àwọn ọmọ Aaroni, fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ OLUWA. Àwọn akọ mààlúù ni wọ́n kọ́kọ́ pa, àwọn alufaa gba ẹ̀jẹ̀ wọn, wọ́n dà á sára pẹpẹ. Lẹ́yìn náà wọ́n pa àwọn àgbò, wọ́n sì da ẹ̀jẹ̀ wọn sára pẹpẹ. Lẹ́yìn náà wọ́n kó àwọn òbúkọ fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wá sọ́dọ̀ ọba ati ìjọ eniyan, wọ́n sì gbé ọwọ́ lé wọn lórí. Àwọn alufaa pa àwọn òbúkọ náà, wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọn rúbọ lórí pẹpẹ fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo ọmọ Israẹli, nítorí ọba ti pàṣẹ pé wọ́n gbọdọ̀ rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo eniyan. Ọba pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ Lefi dúró ninu ilé OLUWA pẹlu ohun èlò orin bíi kimbali, hapu ati dùùrù, gẹ́gẹ́ bí i àṣẹ tí OLUWA pa, láti ẹnu Dafidi ati wolii Gadi tí í ṣe aríran ọba, ati wolii Natani. Àwọn ọmọ Lefi dúró pẹlu ohun èlò orin Dafidi, àwọn alufaa sì dúró pẹlu fèrè. Hesekaya pàṣẹ pé kí wọ́n rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ. Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí rú ẹbọ náà, àwọn akọrin bẹ̀rẹ̀ sí kọrin sí OLUWA pẹlu fèrè ati àwọn ohun èlò orin Dafidi, ọba Israẹli. Ọba ati ìjọ eniyan bá bẹ̀rẹ̀ sí sin OLUWA, àwọn akọrin ń kọrin, àwọn afunfèrè ń fun fèrè títí tí ẹbọ sísun náà fi parí. Nígbà tí wọ́n rú ẹbọ sísun tán, ọba ati ìjọ eniyan wólẹ̀, wọ́n sin Ọlọrun. Ọba ati àwọn ìjòyè pàṣẹ fún àwọn ọmọ Lefi pé kí wọ́n kọ orin ìyìn Dafidi ati ti Asafu, aríran. Wọ́n fi ayọ̀ kọ orin ìyìn náà, wọ́n wólẹ̀, wọ́n sì sin OLUWA. Hesekaya bá sọ fún wọn pé: “Nisinsinyii tí ẹ ti ya ara yín sọ́tọ̀ fún OLUWA, ẹ wá, kí ẹ sì mú ọrẹ ati ẹbọ ọpẹ́ wá sí ilé OLUWA.” Ìjọ eniyan sì mú ọrẹ ati ẹbọ ọpẹ́ wá, àwọn tí wọ́n fẹ́ sì mú ẹbọ sísun wá. Àwọn nǹkan tí wọn mú wá jẹ́ aadọrin akọ mààlúù, ọgọrun-un (100) àgbò, igba (200) ọ̀dọ́ aguntan, gbogbo rẹ̀ wà fún ẹbọ sísun sí OLUWA. Àwọn ẹran tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún ẹbọ jẹ́ ẹgbẹta (600) akọ mààlúù, ati ẹgbẹẹdogun (3,000) aguntan. Àwọn alufaa kò pọ̀ tó láti pa gbogbo ẹran náà, nítorí náà, kí ó tó di pé àwọn alufaa mìíràn yóo ya ara wọn sí mímọ́, àwọn arakunrin wọn, àwọn ọmọ Lefi, ràn wọ́n lọ́wọ́ títí iṣẹ́ náà fi parí. Àwọn ọmọ Lefi ṣe olóòótọ́ ní yíya ara wọn sí mímọ́ ju àwọn alufaa lọ. Yàtọ̀ sí ọpọlọpọ ẹbọ sísun, wọ́n fi ọ̀rá rú ẹbọ alaafia ati ẹbọ ohun mímu fún ẹbọ sísun. Bẹ́ẹ̀ ni iṣẹ́ ìsìn ninu ilé OLUWA ṣe tún bẹ̀rẹ̀. Hesekaya ati ìjọ eniyan yọ̀ nítorí ohun tí Ọlọrun ṣe fún wọn, nítorí láìròtẹ́lẹ̀ ni gbogbo rẹ̀ bẹ̀rẹ̀. Hesekaya ranṣẹ sí gbogbo Juda ati Israẹli. Ó kọ̀wé sí Efuraimu ati Manase pẹlu, pé kí gbogbo wọ́n wá sí ilé OLUWA ní Jerusalẹmu láti wá ṣe Àjọ Ìrékọjá ní orúkọ OLUWA Ọlọrun Israẹli. Ọba, àwọn ìjòyè, ati àwọn eniyan ní Jerusalẹmu ti pinnu láti ṣe àjọ náà ní oṣù keji. Ṣugbọn wọn kò lè ṣe é ní àkókò rẹ̀ nítorí àwọn alufaa tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ kò tíì pọ̀ tó, àwọn eniyan kò sì tíì péjọ sí Jerusalẹmu tán. Ìpinnu yìí dára lójú ọba ati gbogbo ìjọ eniyan. Wọ́n bá pàṣẹ pé kí wọ́n kéde jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Israẹli láti Beeriṣeba títí dé Dani, pé kí àwọn eniyan wá sí Jerusalẹmu láti pa Àjọ Ìrékọjá mọ́ fún OLUWA Ọlọrun Israẹli; nítorí pé wọn kò tíì ṣe Àjọ Ìrékọjá náà pẹlu ọ̀pọ̀ eniyan gẹ́gẹ́ bí ìlànà. Àwọn oníṣẹ́ lọ jákèjádò Israẹli ati Juda, pẹlu ìwé láti ọ̀dọ̀ ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba. Wọ́n kọ sinu ìwé náà pé: “Ẹ̀yin eniyan Israẹli, ẹ pada sọ́dọ̀ OLUWA, Ọlọrun Abrahamu, Isaaki, ati Israẹli, kí ó lè pada sọ́dọ̀ ẹ̀yin tí ẹ kù tí ẹ sá àsálà, tí ọba Asiria kò pa. Ẹ má dàbí àwọn baba yín ati àwọn arakunrin yín tí wọ́n ṣe alaiṣootọ sí OLUWA, Ọlọrun àwọn baba wọn, tí ó sì sọ ilẹ̀ wọn di ahoro bí ẹ ti rí i yìí. Ẹ má ṣe oríkunkun, bí àwọn baba yín. Ẹ fi ara yín fún OLUWA, kí ẹ wá sí ibi mímọ́ rẹ̀, tí ó ti yà sọ́tọ̀ títí lae. Ẹ wá sin OLUWA Ọlọrun yín níbẹ̀, kí ibinu rẹ̀ lè yipada kúrò lọ́dọ̀ yín. Bí ẹ bá pada sọ́dọ̀ OLUWA, àwọn arakunrin yín ati àwọn ọmọ yín yóo rí àánú lọ́dọ̀ àwọn tí ó kó wọn lẹ́rú, wọn yóo sì dá wọn pada sí ilẹ̀ yìí. Nítorí olóore ọ̀fẹ́ ati aláàánú ni OLUWA Ọlọrun yín, kò ní kẹ̀yìn si yín bí ẹ bá pada sọ́dọ̀ rẹ̀.” Àwọn oníṣẹ́ ọba lọ láti ìlú kan dé ekeji jákèjádò ilẹ̀ Efuraimu ati ti Manase, títí dé ilẹ̀ Sebuluni. Ṣugbọn àwọn eniyan fi wọ́n rẹ́rìn-ín, wọ́n sì fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà. Àfi díẹ̀ ninu àwọn ará Aṣeri, Manase, ati Sebuluni ni wọ́n rẹ ara wọn sílẹ̀, tí wọ́n wá sí Jerusalẹmu. Ọlọrun lọ́wọ́ sí ohun tí àwọn ará Juda ń ṣe, ó fi sí wọn ní ọkàn láti mú àṣẹ tí ọba ati àwọn olórí pa fún wọn ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA. Ogunlọ́gọ̀ eniyan péjọ ní Jerusalẹmu ní oṣù keji láti ṣe Àjọ Àìwúkàrà. Wọ́n wó gbogbo pẹpẹ oriṣa ati àwọn pẹpẹ turari tí ó wà ní Jerusalẹmu, wọ́n dà wọ́n sí àfonífojì Kidironi. Wọ́n pa ọ̀dọ́ aguntan Àjọ Ìrékọjá ní ọjọ́ kẹrinla oṣù keji. Ojú ti àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi tí wọn kò tíì ya ara wọn sí mímọ́, tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n tètè lọ ya ara wọn sí mímọ́, tí wọ́n sì mú ẹbọ sísun wá sí ilé OLUWA. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi ara wọn sí ipò tí ó yẹ kí wọ́n wà, gẹ́gẹ́ bí òfin Mose, eniyan Ọlọrun; àwọn alufaa bẹ̀rẹ̀ sí wọ́n ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Lefi sí orí pẹpẹ. Àwọn tí wọn kò tíì ya ara wọn sí mímọ́ pọ̀ níbi àpéjọ náà, nítorí náà, àwọn ọmọ Lefi bá wọn pa ẹran wọn kí àwọn ẹran náà lè jẹ́ mímọ́ fún OLUWA. Ogunlọ́gọ̀ eniyan, pataki jùlọ ọpọlọpọ ninu àwọn tí wọn wá láti Efuraimu, Manase, Isakari ati Sebuluni, kò tíì ya ara wọn sí mímọ́, sibẹ wọ́n jẹ àsè Àjọ Ìrékọjá, ṣugbọn kì í ṣe ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Ṣugbọn Hesekaya gbadura fún wọn pé: “Kí OLUWA rere dáríjì gbogbo àwọn tí wọ́n fi tọkàntọkàn wá OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè má jẹ́ ọ̀nà ẹ̀tọ́ ni wọ́n fi jẹ àsè àjọ náà gẹ́gẹ́ bí òfin ìwẹ̀nùmọ́ ti ibi mímọ́.” OLUWA gbọ́ adura Hesekaya, ó sì wo àwọn eniyan náà sàn. Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu pa Àjọ Àìwúkàrà mọ́ fún ọjọ́ meje pẹlu ayọ̀ ńlá. Àwọn ọmọ Lefi ati àwọn alufaa ń kọrin ìyìn sí OLUWA lojoojumọ pẹlu gbogbo agbára wọn. Hesekaya gba àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ṣe dáradára ninu iṣẹ́ OLUWA níyànjú. Àwọn eniyan náà jẹ àsè àjọ náà fún ọjọ́ meje, wọ́n ń rú ẹbọ alaafia, wọ́n sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn. Gbogbo wọn tún pinnu láti pa àjọ náà mọ́ fún ọjọ́ meje sí i, wọ́n sì fi tayọ̀tayọ̀ ṣe é. Hesekaya, ọba fún àwọn eniyan náà ní ẹgbẹrun (1,000) akọ mààlúù ati ẹẹdẹgbaarin (7,000) aguntan láti fi rúbọ. Àwọn ìjòyè náà fún àwọn eniyan ní ẹgbẹrun (1,000) akọ mààlúù, ati ẹgbaarun (10,000) aguntan. Ọpọlọpọ àwọn alufaa ni wọ́n wá, tí wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́. Gbogbo àwọn ará Juda, ati àwọn alufaa, ati àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn onílé ati àwọn àlejò tí wọ́n wá láti ilẹ̀ Israẹli ati àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ Juda, gbogbo wọn ni wọ́n kún fún ayọ̀. Gbogbo Jerusalẹmu kún fún ayọ̀ nítorí kò tíì tún sí irú rẹ̀ mọ́ láti ìgbà Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli. Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi dìde, wọ́n súre fún àwọn eniyan; OLUWA gbọ́ ohùn wọn, adura wọn sì gòkè lọ sí ibùgbé mímọ́ rẹ̀ lọ́run. Nígbà tí wọ́n parí ayẹyẹ wọnyi, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wá síbi àjọ náà lọ sí àwọn ìlú Juda, wọ́n fọ́ gbogbo òpó oriṣa, ati gbogbo igbó oriṣa Aṣera, wọ́n wó gbogbo àwọn pẹpẹ palẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ Juda, ti Bẹnjamini, ti Efuraimu ati ti Manase. Nígbà tí wọ́n fọ́ gbogbo wọn túútúú tán, wọ́n pada lọ sí ìlú wọn, olukuluku sì lọ sí orí ilẹ̀ rẹ̀. Hesekaya pín àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́, olukuluku ní iṣẹ́ tirẹ̀. Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi wà fún ẹbọ sísun, ati ẹbọ alaafia. Àwọn náà ni wọ́n wà fún ati máa ṣe iṣẹ́ ìsìn lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ OLUWA, ati láti máa kọrin ọpẹ́ ati ìyìn sí OLUWA. Hesekaya a máa fa ẹran kalẹ̀ ninu agbo ẹran rẹ̀ fún ẹbọ sísun ti àárọ̀ ati ti àṣáálẹ́, ati fún ẹbọ ọjọ́ ìsinmi, ẹbọ oṣù tuntun ati àwọn ẹbọ mìíràn gẹ́gẹ́ bí òfin OLUWA. Ọba pàṣẹ fún àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu pé kí wọ́n mú ọrẹ tí ó tọ́ sí àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi wa, kí wọ́n lè fi gbogbo àkókò wọn sílẹ̀ láti máa kọ́ àwọn eniyan ní òfin OLUWA. Ní kété tí àṣẹ yìí tàn káàkiri, wọ́n mú ọpọlọpọ àkọ́so ọkà, ati ọtí ati òróró ati oyin, ati àwọn nǹkan irè oko mìíràn wá. Wọ́n tún san ìdámẹ́wàá gbogbo nǹkan tí wọ́n ní. Àwọn ọmọ Israẹli ati ti Juda tí wọn ń gbé àwọn ìlú Juda náà san ìdámẹ́wàá mààlúù ati aguntan, ati ti àwọn ohun mímọ́ tí wọ́n ti yà sọ́tọ̀ fún OLUWA Ọlọrun wọn, wọ́n kó wọn jọ bí òkítì. Ní oṣù kẹta ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn ìdámẹ́wàá náà jọ, wọ́n kó wọn jọ tán ní oṣù keje. Nígbà tí Hesekaya ati àwọn ìjòyè wá wo àwọn ìdámẹ́wàá tí wọ́n kójọ bí òkítì, wọ́n yin OLUWA, wọ́n sì dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ Israẹli. Hesekaya bèèrè lọ́wọ́ àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi nípa àwọn òkítì náà. Asaraya, olórí alufaa, láti ìdílé Sadoku dá a lóhùn pé: “Láti ìgbà tí àwọn eniyan ti bẹ̀rẹ̀ sí mú ẹ̀bùn wá sí ilé OLUWA ni a ti ń jẹ àjẹyó, tí ó sì ń ṣẹ́kù, nítorí pé OLUWA ti bukun àwọn eniyan rẹ̀, ni a fi ní àjẹṣẹ́kù tí ó pọ̀ tó yìí.” Hesekaya bá pàṣẹ pé kí wọ́n tọ́jú àwọn yàrá tó wà ninu ilé OLUWA, wọ́n bá ṣe ìtọ́jú wọn. Wọ́n ṣolóòótọ́ ní kíkó àwọn ẹ̀bùn, ati ìdámẹ́wàá àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ náà pamọ́. Konanaya, ọmọ Lefi, ni olórí àwọn tí wọn ń bojútó wọn, Ṣimei, arakunrin rẹ̀ ni igbákejì rẹ̀. Jehieli, Asasaya, ati Nahati; Asaheli, Jerimotu, ati Josabadi; Elieli, Isimakaya, ati Mahati ati Bẹnaya ni àwọn alabojuto tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ Konanaya ati Ṣimei, arakunrin rẹ̀. Hesekaya ọba ati Asaraya olórí ilé OLUWA ni wọ́n yàn wọ́n sí iṣẹ́ náà. Kore, ọmọ Imina, ọmọ Lefi kan tí ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ìlà oòrùn tẹmpili ni ó ń ṣe alákòóso ọrẹ àtinúwá tí wọ́n mú wá fún Ọlọrun. Òun ni ó sì ń pín àwọn ẹ̀bùn tí a yà sọ́tọ̀ fún OLUWA ati àwọn ọrẹ mímọ́ jùlọ. Edẹni, Miniamini, ati Jeṣua, Ṣemaaya, Amaraya, ati Ṣekanaya, ń ràn án lọ́wọ́ ní gbogbo ìlú àwọn alufaa, wọ́n ń pín àwọn ẹ̀bùn náà láì ṣe ojuṣaaju àwọn arakunrin wọn, lọ́mọdé ati lágbà ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí; àfi àwọn ọkunrin, láti ẹni ọdún mẹta sókè, tí wọ́n ti kọ orúkọ wọn sílẹ̀ ní ìdílé ìdílé, gbogbo awọn tí wọ́n wọ ilé OLUWA gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ olukuluku ṣe gbà lójoojúmọ́, fun iṣẹ́ ìsìn wọn gẹ́gẹ́ bí ipò wọn, nípa ìpín wọn. Wọ́n kọ orúkọ àwọn alufaa ní ìdílé ìdílé, ṣugbọn àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún sókè ni wọ́n kọ orúkọ wọn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ipò wọn ati ìpín wọn. Àwọn alufaa kọ orúkọ wọn sílẹ̀ pẹlu àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn, àwọn aya wọn, àwọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin gbogbo wọn patapata, nítorí pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́ nípa pípa ara wọn mọ́. Ninu àwọn alufaa tí wọ́n wà ní ìlú àwọn ìran Aaroni ní ilẹ̀ gbogbogbòò ati ninu ìletò wọn, ni àwọn olóòótọ́ wà, tí wọ́n yàn láti máa pín oúnjẹ fún olukuluku ninu àwọn alufaa ati àwọn tí orúkọ wọn wà ninu àkọsílẹ̀ ìdílé àwọn Lefi. Jákèjádò Juda ni Hesekaya ti ṣe ètò yìí, ó ṣe ohun tí ó dára, tí ó tọ́, tí ó sì jẹ́ òtítọ́ lójú OLUWA Ọlọrun rẹ̀. Gbogbo ohun tí ó ṣe ninu iṣẹ́ ìsìn ilé OLUWA, gẹ́gẹ́ bí òfin ati àṣẹ Ọlọ́run, ati wíwá tí ó wá ojurere Ọlọrun, gbogbo rẹ̀ ni ó ṣe tọkàntọkàn, ó sì dára fún un. Lẹ́yìn gbogbo nǹkan tí Hesekaya ṣe, tí ó sin OLUWA pẹlu òtítọ́, Senakeribu ọba Asiria wá gbógun ti Juda. Ó dó ti àwọn ìlú olódi wọn, ó lérò pé òun óo jagun gbà wọ́n. Nígbà tí Hesekaya rí i pé Senakeribu ti pinnu láti gbógun ti Jerusalẹmu, ó jíròrò pẹlu àwọn òṣìṣẹ́ ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀ bí wọn yóo ti ṣe dí ìṣàn omi tí ó wà lẹ́yìn odi ìlú; wọ́n sì ràn án lọ́wọ́. Wọ́n kó ọpọlọpọ eniyan jọ, wọ́n dí àwọn orísun omi ati àwọn odò tí ń ṣàn ní ilẹ̀ náà. Wọ́n ní, “Kò yẹ kí ọba Asiria wá, kí ó bá omi tí ó tó báyìí.” Ọba yan àwọn òṣìṣẹ́ láti mọ gbogbo àwọn odi tí ó wó lulẹ̀, ati láti kọ́ ilé ìṣọ́ sí orí wọn. Wọ́n tún mọ odi mìíràn yípo wọn. Ó tún Milo tí ó wà ní ìlú Dafidi ṣe kí ó fi lágbára síi, ó sì pèsè ọpọlọpọ nǹkan ìjà ati apata. Ọba yan àwọn ọ̀gágun lórí àwọn eniyan, ó sì pe gbogbo wọn jọ sí gbàgede ẹnubodè ìlú. Ó dá wọn lọ́kàn le, ó ní, “Ẹ múra, ẹ ṣọkàn gírí. Ẹ má bẹ̀rù, ẹ má sì jáyà níwájú ọba Asiria ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ bí wọ́n tilẹ̀ pọ̀; nítorí agbára ẹni tí ó wà pẹlu wa ju ti àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ lọ. Agbára ti ẹran ara ni àwọn ọmọ ogun tirẹ̀ ní, ṣugbọn OLUWA Ọlọrun ni ó wà pẹlu wa láti ràn wá lọ́wọ́ ati láti jà fún wa.” Ọ̀rọ̀ tí Hesekaya ọba Juda sọ sì fi àwọn eniyan rẹ̀ lọ́kàn balẹ̀. Lẹ́yìn èyí, nígbà tí Senakeribu ati àwọn ogun rẹ̀ gbógun ti Lakiṣi, ó ranṣẹ sí Hesekaya ọba Juda ati àwọn ará Juda tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu pé, “Òun Senakeribu, ọba Asiria ní, kí ni wọ́n gbójú lé tí wọ́n fi dúró sí Jerusalẹmu, ìlú tí ogun dó tì? Ó ní bí Hesekaya bá ní OLUWA Ọlọrun wọn yóo gbà wọ́n lọ́wọ́ òun ọba Asiria, ó ń ṣì wọ́n lọ́nà ni, ó fẹ́ kí òùngbẹ ati ebi pa wọ́n kú ni. Ó ní, Ṣebí Hesekaya yìí kan náà ni ó kó gbogbo oriṣa kúrò ní Jerusalẹmu ati ní Juda tí ó sọ fún wọn pé ibi pẹpẹ kan ṣoṣo ni wọ́n ti gbọdọ̀ máa jọ́sìn, kí wọn sì máa rúbọ níbẹ̀? Ó ní ǹjẹ́ wọ́n mọ ohun tí òun ati baba òun ti ṣe sí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn? Ati pé, ǹjẹ́ àwọn oriṣa àwọn orílẹ̀-èdè náà gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ ọba Asiria? Ó ní èwo ni oriṣa wọn gbà sílẹ̀ lọ́wọ́ òun, ninu gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi tí baba òun parun, tí Ọlọrun tiyín yóo fi wá gbà yín? Ó ní nítorí náà, kí wọn má ṣe jẹ́ kí Hesekaya tàn wọ́n jẹ, tabi kí ó ṣì wọ́n lọ́nà báyìí. Ó ní kí wọn má gbọ́ ohun tí ó ń sọ rárá, nítorí pé kò sí oriṣa orílẹ̀-èdè kan tí ó tó gba àwọn eniyan rẹ̀ lọ́wọ́ òun tabi lọ́wọ́ àwọn baba òun, kí á má wá sọ pé Ọlọrun tiwọn yóo gbà wọ́n lọ́wọ́ òun.” Àwọn iranṣẹ ọba Asiria tún sọ ọ̀rọ̀ burúkú sí OLUWA Ọlọrun ati sí Hesekaya, iranṣẹ rẹ̀. Ọba Asiria yìí kọ àwọn ìwé àfojúdi kan sí OLUWA Ọlọrun Israẹli, ó ní, “Gẹ́gẹ́ bí àwọn oriṣa àwọn orílẹ̀-èdè yòókù kò ti lè gba àwọn eniyan wọn kúrò lọ́wọ́ mi, bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun Hesekaya náà kò ní lè gba àwọn eniyan rẹ̀ lọ́wọ́ mi.” Àwọn iranṣẹ ọba Asiria kígbe sókè nígbà tí wọ́n sọ ọ̀rọ̀ ní èdè Heberu, sí àwọn ará Jerusalẹmu tí wọ́n wà lórí odi, wọn fi dẹ́rùbà wọ́n kí wọ́n lè gba ìlú náà. Wọ́n sọ̀rọ̀ Ọlọrun Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn oriṣa àtọwọ́dá tí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ń bọ. Hesekaya ati wolii Aisaya, ọmọ Amosi bá fi ìtara gbadura sí Ọlọrun nípa ọ̀rọ̀ yìí. OLUWA bá rán angẹli kan lọ pa gbogbo akọni ọmọ ogun, ati àwọn ọ̀gágun ati àwọn olórí ogun Asiria ní ibùdó wọn. Nítorí náà, pẹlu ìtìjú ńlá ni Senakeribu fi pada lọ sí ìlú rẹ̀. Nígbà tí ó wọ inú ilé oriṣa lọ, àwọn kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin bá fi idà pa á. Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe gba Hesekaya ati àwọn ará Jerusalẹmu sílẹ̀ lọ́wọ́ Senakeribu, ọba Asiria, ati gbogbo àwọn ọ̀tá Hesekaya, ó sì fún un ní alaafia. Ọpọlọpọ eniyan mú ẹ̀bùn wá fún OLUWA ní Jerusalẹmu, wọ́n sì mú ẹ̀bùn olówó iyebíye wá fún Hesekaya, ọba Juda. Láti ìgbà náà lọ, àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri bẹ̀rẹ̀ sí kókìkí rẹ̀. Ní àkókò kan, Hesekaya ṣàìsàn, ó fẹ́rẹ̀ kú. Ó gbadura, sí OLUWA, OLUWA sì gbọ́ adura rẹ̀, ó sì fún un ní àmì tí ó yani lẹ́nu kan, ṣugbọn Hesekaya ṣe ìgbéraga, kò fi ẹ̀mí ìmoore hàn fún ohun tí Ọlọrun ṣe fún un. Nítorí náà, inú bí OLUWA sí àtòun ati Juda ati Jerusalẹmu. Hesekaya ati àwọn ará Jerusalẹmu bá rẹ ara wọn sílẹ̀, wọ́n sì ronupiwada. Nítorí náà, OLUWA kò bínú sí wọn mọ́ ní ìgbà ayé Hesekaya. Hesekaya ní ọpọlọpọ ọrọ̀ ati ọlá. Ó kọ́ ilé ìṣúra tí ó kó fadaka, ati wúrà, ati òkúta olówó iyebíye, ati turari sí, ati apata ati gbogbo nǹkan olówó iyebíye. Ó kọ́ àká fún ọkà, ọtí waini, ati òróró; ó ṣe ibùjẹ fún oríṣìíríṣìí mààlúù, ó sì ṣe ọgbà fún àwọn aguntan ati ewúrẹ́. Bákan náà, ó kọ́ ọpọlọpọ ìlú fún ara rẹ̀, ó sì ní agbo ẹran lọpọlọpọ, nítorí Ọlọrun ti fún un ní ọrọ̀ lọpọlọpọ. Hesekaya náà ló dí ẹnu odò Gihoni ní apá òkè, ó ya omi rẹ̀ wọ ìhà ìwọ̀ oòrùn ìlú Dafidi. Hesekaya sì ń ní ìlọsíwájú ninu gbogbo iṣẹ́ rẹ̀. Nígbà tí àwọn olórí ilẹ̀ Babiloni ranṣẹ sí i láti mọ̀ nípa ohun ìyanu tí ó ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ náà, Ọlọrun fi sílẹ̀ láti dán an wò, kí Ọlọrun lè mọ gbogbo ohun tí ó wà lọ́kàn rẹ̀. Àkọsílẹ̀ gbogbo nǹkan yòókù tí Hesekaya ṣe, ati iṣẹ́ rere rẹ̀, wà ninu ìwé ìran wolii Aisaya, ọmọ Amosi ati ninu ìwé ìtàn àwọn ọba Juda ati Israẹli. Nígbà tí Hesekaya kú, wọ́n sin ín sí ara òkè, ninu ibojì àwọn ọmọ Dafidi. Gbogbo àwọn eniyan Juda ati ti Jerusalẹmu ṣe ẹ̀yẹ fún un. Manase, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Ọmọ ọdún mejila ni Manase nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún marundinlọgọta. Ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA. Gbogbo nǹkan ẹ̀gbin tí àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA lé jáde fún àwọn ọmọ Israẹli máa ń ṣe ni òun náà ṣe. Gbogbo ibi ìrúbọ tí Hesekaya, baba rẹ̀ ti wó lulẹ̀ ni ó tún kọ́. Ó tẹ́ pẹpẹ fún Baali, ó sì ri àwọn òpó fún Aṣera. Ó ń bọ àwọn ìràwọ̀, ó sì ń sìn wọ́n. Ó tẹ́ pẹpẹ oriṣa sinu ilé OLUWA, ilé tí OLUWA ti sọ nípa rẹ̀ pé, “Ní Jerusalẹmu ni ibi ìjọ́sìn tí orúkọ mi yóo wà, tí ẹ óo ti máa sìn mí títí lae.” Ó tẹ́ pẹpẹ sinu gbọ̀ngàn meji tí ó wà ninu tẹmpili, wọ́n sì ń bọ àwọn ìràwọ̀ ati gbogbo ohun tí ó wà lójú ọ̀run níbẹ̀. Ó fi àwọn ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ sísun ní àfonífojì ọmọ Hinomu. Ó ń lo àfọ̀ṣẹ, ó ń woṣẹ́, a sì máa lọ sọ́dọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀. Ó dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA tóbẹ́ẹ̀ tí inú OLUWA fi bẹ̀rẹ̀ sí ru. Ó gbé ère oriṣa tí ó gbẹ́ wá sí ilé Ọlọrun, ilé tí Ọlọrun ti sọ nípa rẹ̀ fún Dafidi ati Solomoni, ọmọ rẹ̀ pé, “Ninu ilé yìí ati ní Jerusalẹmu tí mo ti yàn láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli mejeejila ni wọn yóo ti máa sìn mí. Bí àwọn ọmọ Israẹli bá pa òfin mi mọ́, tí wọ́n sì tẹ̀lé gbogbo ìlànà ati ìdájọ́ mi tí mo fún wọn láti ọwọ́ Mose, n kò ní ṣí wọn nídìí mọ́ lórí ilẹ̀ tí mo ti yàn fún àwọn baba wọn.” Manase ṣi àwọn ará Juda ati Jerusalẹmu lọ́nà, tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ṣe burúkú ju àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA parun fún Israẹli lọ. OLUWA kìlọ̀ fún Manase ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀, ṣugbọn wọ́n kọ̀, wọn kò gbọ́. Nítorí náà, OLUWA mú kí ọ̀gágun ilẹ̀ Asiria wá ṣẹgun Juda, wọ́n fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà de Manase, wọ́n fi ìwọ̀ mú un, wọ́n sì fà á lọ sí Babiloni. Nígbà tí ó wà ninu ìpọ́njú ó wá ojurere OLUWA Ọlọrun, ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ patapata níwájú Ọlọrun àwọn baba rẹ̀. Ó gbadura sí OLUWA, OLUWA gbọ́ adura rẹ̀, ó sì mú un pada wá sórí ìtẹ́ rẹ̀ ní Jerusalẹmu. Ó wá mọ̀ nígbà náà pé OLUWA ni Ọlọrun. Lẹ́yìn náà ó mọ odi ìta sí ìlú Dafidi, ní apá ìwọ̀ oòrùn Gihoni, ní àfonífojì, ati sí ẹnubodè ẹja; ó mọ ọ́n tí ó ga yípo Ofeli. Ó kó àwọn ọ̀gágun sinu àwọn ìlú olódi ní Juda. Ó kó àwọn oriṣa ati àwọn ère kúrò ninu ilé OLUWA, ati gbogbo ojúbọ oriṣa tí ó kọ́ sórí òkè níbi tí ilé OLUWA wà, ati àwọn tí wọ́n kọ́ káàkiri gbogbo ìlú Jerusalẹmu. Ó da gbogbo wọn sẹ́yìn odi ìlú. Ó tún pẹpẹ OLUWA tẹ́ sí ipò rẹ̀, ó rú ẹbọ alaafia ati ẹbọ ọpẹ́ lórí rẹ̀, ó sì pàṣẹ fún àwọn eniyan Juda pé kí wọ́n máa sin OLUWA Ọlọrun Israẹli. Sibẹsibẹ àwọn eniyan ṣì ń rúbọ ní àwọn ibi ìrúbọ, ṣugbọn OLUWA Ọlọrun wọn ni wọ́n ń rúbọ sí. Àkọsílẹ̀ àwọn nǹkan yòókù tí Manase ṣe, ati adura rẹ̀ sí Ọlọrun, ati àwọn ọ̀rọ̀ tí aríran sọ fún un ní orúkọ OLUWA, Ọlọrun Israẹli, gbogbo rẹ̀ wà ninu ìwé ìtàn àwọn ọba Israẹli. Adura rẹ̀ sí Ọlọrun, ati bí Ọlọrun ṣe dá a lóhùn, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ati aiṣododo rẹ̀, wà ninu ìwé Ìtàn Àwọn Aríran. Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo ibi tí ó kọ́ pẹpẹ ìrúbọ rẹ̀ sí, àwọn ère tí ó gbẹ́ fún Aṣera, ati àwọn ère tí ó ń sìn kí ó tó ronupiwada. Nígbà tí ó kú, wọ́n sin ín sí ààfin rẹ̀. Amoni, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Ọmọ ọdún mejilelogun ni Amoni nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè fún ọdún meji ní Jerusalẹmu. Ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, bíi Manase, baba rẹ̀, ó rúbọ sí gbogbo oriṣa tí baba rẹ̀ ṣe, ó sì ń bọ wọ́n. Kò fi ìgbà kankan ronupiwada bí baba rẹ̀ ti ṣe níwájú OLUWA. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀ ni ó ń dá kún ẹ̀ṣẹ̀. Nígbà tí ó yá, àwọn ọ̀gágun rẹ̀ dìtẹ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì pa á ní ààfin rẹ̀. Ṣugbọn gbogbo àwọn ará ilẹ̀ Juda pa àwọn tí wọ́n pa Amoni ọba, wọ́n sì fi Josaya ọmọ rẹ̀ jọba. Ọmọ ọdún mẹjọ ni Josaya nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkanlelọgbọn. Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA. Ó tẹ̀lé àpẹẹrẹ Dafidi, baba ńlá rẹ̀, nípa títẹ̀lé òfin Ọlọrun fínnífínní. Ní ọdún kẹjọ tí Josaya gorí oyè, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọde ni, ó bẹ̀rẹ̀ sí sin Ọlọrun Dafidi, baba ńlá rẹ̀. Ní ọdún kejila, ó bẹ̀rẹ̀ sí wó àwọn pẹpẹ oriṣa ní gbogbo ilẹ̀ Juda ati Jerusalẹmu. Ó wó àwọn òpó oriṣa Aṣera, ó sì fọ́ àwọn ère gbígbẹ́ ati èyí tí wọ́n rọ. Wọ́n wó àwọn oriṣa Baali lulẹ̀ níwájú rẹ̀; ó fọ́ àwọn pẹpẹ turari tí wọ́n wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ó wó àwọn òpó oriṣa Aṣera ati gbogbo àwọn ère tí wọ́n fi igi gbẹ́ ati àwọn tí wọ́n fi irin rọ. Ó fọ́ wọn túútúú, ó sì fọ́n wọn ká sórí ibojì àwọn tí wọn ń sìn wọ́n. Ó sun egungun àwọn babalóòṣà lórí pẹpẹ oriṣa wọn. Bẹ́ẹ̀ ló ṣe fọ Jerusalẹmu ati Juda mọ́ tónítóní. Bákan náà ni ó ṣe ní àwọn ìlú Manase, ati ti Efuraimu, ati àwọn ìlú ilẹ̀ Simeoni títí dé ilẹ̀ Nafutali, ati ní gbogbo àyíká wọn. Ó wó àwọn pẹpẹ, ó lọ àwọn òpó Aṣera ati àwọn ère oriṣa lúúlúú, ó sì wó gbogbo pẹpẹ turari jákèjádò ilẹ̀ Israẹli. Lẹ́yìn náà ó pada sí Jerusalẹmu. Ní ọdún kejidinlogun ìjọba Josaya, lẹ́yìn tí ó ti pa ìbọ̀rìṣà rẹ́ ní ilẹ̀ náà, ó rán Ṣafani ọmọ Asalaya láti tún ilé OLUWA Ọlọrun rẹ̀ ṣe pẹlu Maaseaya, gomina ìlú, ati Joa, ọmọ Joahasi tí ó jẹ́ alákòóso ìwé ìrántí. Wọ́n lọ sọ́dọ̀ Hilikaya, olórí alufaa, wọ́n kó owó tí àwọn eniyan mú wá sí ilé OLUWA fún un, tí àwọn Lefi tí wọn ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà gbà lọ́wọ́ àwọn ẹ̀yà Manase, ati Efuraimu ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli yòókù, ati lọ́wọ́ àwọn tí wọn ń gbé Juda, Bẹnjamini ati Jerusalẹmu. Wọ́n kó owó náà fún àwọn tí ń ṣe àbojútó iṣẹ́ náà. Àwọn ni wọ́n ń sanwó fún àwọn tí wọn ń tún ilé OLUWA ṣe. Wọ́n sanwó fún àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà ati àwọn tí wọn ń mọlé, láti ra òkúta gbígbẹ́ ati pákó ati igi, kí wọ́n fi tún àwọn ilé tí àwọn ọba Juda ti sọ di àlàpà kọ́. Àwọn eniyan náà fi òtítọ́ inú ṣe iṣẹ́ náà. Àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń ṣàkóso wọn ni: Jahati ati Ọbadaya, láti inú ìran Merari, ati Sakaraya ati Meṣulamu, láti inú ìran Kohati. Àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n mọ̀ nípa ohun èlò orin ni wọ́n ń ṣàkóso àwọn tí wọn ń ru ẹrù, ati àwọn tí wọn ń ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ mìíràn. Àwọn kan ninu àwọn ọmọ Lefi jẹ́ akọ̀wé, àwọn kan wà nídìí ètò ìsìn, àwọn mìíràn sì jẹ́ aṣọ́nà. Nígbà tí wọn ń kó owó tí àwọn eniyan ti mú wá sinu ilé OLUWA jáde, Hilikaya, alufaa rí ìwé òfin OLUWA tí Ọlọrun fún Mose. Hilikaya sọ fún Ṣafani akọ̀wé, ó ní, “Mo rí ìwé òfin ninu ilé OLUWA.” Ó fún Ṣafani ní ìwé náà, Ṣafani sì mú un lọ sọ́dọ̀ ọba, ó ní, “Àwọn iranṣẹ ń ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí àṣẹ rẹ. Wọ́n ti kó owó tí wọ́n rí ninu ilé OLUWA jọ, wọ́n sì ti kó o fún àwọn tí wọn ń ṣe àkóso iṣẹ́ náà ati àwọn òṣìṣẹ́;” ati pé, “Hilikaya, alufaa, fún mi ní ìwé kan.” Ṣafani sì kà á níwájú ọba. Nígbà tí ọba gbọ́ ohun tí ó wà ninu ìwé òfin náà, ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbẹ̀rù ati ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn. Ó pàṣẹ fún Hilikaya, Ahikamu, ọmọ Ṣafani, Abidoni, ọmọ Mika, ati Ṣafani, akọ̀wé, ati Asaya, iranṣẹ ọba, pé, “Ẹ tọ Ọlọrun lọ fún èmi ati àwọn eniyan tí wọ́n kù ní Juda ati ní Israẹli, ẹ ṣe ìwádìí ohun tí a kọ sinu ìwé náà; nítorí pé àwọn baba ńlá wa tàpá sí ọ̀rọ̀ OLUWA, wọn kò sì ṣe ohun tí a kọ sinu ìwé yìí ni OLUWA ṣe bínú sí wa lọpọlọpọ.” Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba, Hilikaya ati àwọn tí wọ́n tẹ̀lé e, lọ sọ́dọ̀ Hulida, wolii obinrin, iyawo Ṣalumu, ọmọ Tokihati, ọmọ Hasira tí ó jẹ́ alabojuto ibi tí wọn ń kó aṣọ pamọ́ sí ní ìhà keji Jerusalẹmu tí Hulida ń gbé. Wọ́n sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún un. Ó bá dá wọn lóhùn pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ní kí n sọ fun yín, kí ẹ sọ fún ẹni tí ó ran yín sí mi pé òun OLUWA ní òun óo mú ibi wá sórí ibí yìí ati àwọn eniyan ibẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé tí a kà sí ọba Juda létí. Nítorí pé wọ́n ti kọ òun OLUWA sílẹ̀, wọ́n sì ń sun turari sí àwọn oriṣa, kí wọ́n lè fi ìṣe wọn mú òun bínú; nítorí náà òun óo bínú sí ibí yìí, kò sí ẹni tí yóo lè dá ibinu òun dúró. Ó ní kí ẹ sọ ohun tí ẹ ti gbọ́ fún ọba Juda tí ó ranṣẹ láti wá wádìí lọ́wọ́ OLUWA Ọlọrun pé, èmi OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, nítorí pé nígbà tí ó gbọ́ nípa ìyà tí n óo fi jẹ Jerusalẹmu ati àwọn tí ń gbé ibẹ̀, ó ronupiwada, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú mi, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì sọkún níwájú mi, mo sì ti gbọ́ adura rẹ̀. Nítorí náà, ìdájọ́ tí mo ti pinnu sórí Jerusalẹmu kò ní ṣẹlẹ̀ ní ìgbà ayé rẹ̀, ikú wọ́ọ́rọ́ ni yóo sì kú.” Àwọn eniyan náà bá pada lọ jíṣẹ́ fún ọba. Lẹ́yìn náà, Josaya ọba ranṣẹ pe gbogbo àwọn àgbààgbà Juda ati ti Jerusalẹmu. Ó bá lọ sí ilé OLUWA pẹlu gbogbo ará Juda, ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu; ati àwọn alufaa, ati àwọn ọmọ Lefi ati àwọn eniyan yòókù; ati olówó ati talaka. Ọba ka ìwé majẹmu tí wọ́n rí ninu ilé OLUWA sí etígbọ̀ọ́ wọn. Ó dúró ní ààyè rẹ̀, ó sì bá OLUWA dá majẹmu pé òun óo máa fi tọkàntọkàn rìn ní ọ̀nà OLUWA, òun óo máa pa òfin rẹ̀ mọ́, òun óo máa mú àṣẹ rẹ̀ ṣẹ, òun ó sì máa tẹ̀lé ìlànà rẹ̀. Ó ní òun ó máa fi tọkàntọkàn pa majẹmu tí a kọ sinu ìwé náà mọ́. Lẹ́yìn náà, ó ní kí àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini ati àwọn ará Jerusalẹmu bá OLUWA dá majẹmu kí wọ́n sì pa á mọ́. Àwọn ará Jerusalẹmu sì pa majẹmu OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn mọ́. Josaya run gbogbo àwọn ère oriṣa tí wọ́n wà ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli, ó sì mú kí àwọn ọmọ Israẹli sin OLUWA Ọlọrun wọn. Ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, wọn kò yipada kúrò lẹ́yìn OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn. Josaya ṣe Àjọ Ìrékọjá fún OLUWA ní Jerusalẹmu. Ní ọjọ́ kẹrinla, oṣù kinni ni wọ́n pa ọ̀dọ́ aguntan Àjọ Ìrékọjá. Ó yan àwọn alufaa sí ipò wọn, ó sì gbà wọ́n níyànjú kí wọ́n ṣe iṣẹ́ wọn ninu ilé OLUWA. Ó sọ fún àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń kọ́ àwọn ọmọ Israẹli, tí wọ́n sì jẹ́ mímọ́ pé, “Ẹ gbé Àpótí mímọ́ náà sinu ilé tí Solomoni ọmọ Dafidi, ọba Israẹli kọ́. Ẹ kò ní máa gbé e lé èjìká kiri mọ́. Ṣugbọn kí ẹ máa ṣiṣẹ́ fún OLUWA Ọlọrun, ati fún gbogbo eniyan Israẹli. Ẹ kó ara yín jọ ní ìdílé ìdílé ati ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ gẹ́gẹ́ bí ìlànà Dafidi, ọba Israẹli ati ti Solomoni ọmọ rẹ̀. Ẹ dúró ní ibi mímọ́, kí ẹ sì pín ara yín sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé àwọn arakunrin yín. Ìdílé kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ ní àwọn ọmọ Lefi tí wọn yóo wà pẹlu wọn. Kí ẹ pa ọ̀dọ́ aguntan Ìrékọjá, kí ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ múra sílẹ̀ fún àwọn arakunrin yín láti ṣe ohun tí OLUWA sọ láti ẹnu Mose.” Josaya ọba fún gbogbo àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ ní ẹran fún ẹbọ Ìrékọjá. Láti inú agbo ẹran tirẹ̀ ni ó ti mú ẹgbaa mẹẹdogun (30,000) aguntan ati ọmọ ewúrẹ́, ati ẹgbẹẹdogun (3,000) mààlúù fún wọn. Àwọn olóyè náà fi tọkàntọkàn fún àwọn eniyan, ati àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi ní nǹkan. Hilikaya, Sakaraya ati Jehieli, àwọn alákòóso ninu ilé Ọlọrun, fún àwọn alufaa ní ẹgbẹtala (2,600) ọ̀dọ́ aguntan ati ọmọ ewúrẹ́ ati ọọdunrun (300) mààlúù fún ẹbọ Ìrékọjá. Àwọn olórí ninu àwọn ọmọ Lefi: Konanaya pẹlu Ṣemaaya ati Netaneli, àwọn arakunrin rẹ̀; ati Haṣabaya, Jeieli, ati Josabadi, àwọn olóyè ninu ọmọ Lefi dá ẹẹdẹgbaata (5,000) ọ̀dọ́ aguntan, ati ọmọ ewúrẹ́, ati ẹẹdẹgbẹta (500) mààlúù fún àwọn ọmọ Lefi kí wọn fi rú ẹbọ Ìrékọjá. Nígbà tí gbogbo ètò ti parí, àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi dúró ní ààyè wọn gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí ọba pa. Wọ́n pa ọ̀dọ́ aguntan Ìrékọjá, àwọn alufaa wọ́n ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n gbà lára àwọn ẹran náà sórí pẹpẹ, àwọn ọmọ Lefi sì bó awọ àwọn ẹran náà. Wọ́n ya ẹbọ sísun sọ́tọ̀ kí wọ́n lè pín wọn fún gbogbo ìdílé tí ó wà níbẹ̀, kí wọ́n lè fi rúbọ sí OLUWA gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé Mose. Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ṣe pẹlu àwọn mààlúù. Wọ́n sun ọ̀dọ́ aguntan Ìrékọjá gẹ́gẹ́ bí ìlànà. Wọ́n bọ ẹran ẹbọ mímọ́ ninu ìkòkò, ìsaasùn ati apẹ, wọ́n sì pín in fún àwọn eniyan lẹsẹkẹsẹ. Lẹ́yìn náà, wọ́n tọ́jú tiwọn ati ti àwọn alufaa, àwọn ọmọ Aaroni. Nítorí iṣẹ́ ṣíṣe kò jẹ́ kí àwọn alufaa rí ààyè, láti àárọ̀ títí di alẹ́. Wọ́n ń rú ẹbọ sísun, wọ́n sì ń sun ọ̀rá ẹran níná. Nítorí náà ni àwọn ọmọ Lefi fi tọ́jú tiwọn, tí wọ́n sì tọ́jú ti àwọn alufaa, àwọn ọmọ Aaroni. Àwọn akọrin tí wọ́n jẹ́ ọmọ Asafu dúró ní ipò wọn gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Dafidi. Bẹ́ẹ̀ náà ni Asafu, Hemani, ati Jedutuni, aríran ọba. Àwọn aṣọ́nà tẹmpili kò kúrò ní ààyè wọn, nítorí pé àwọn ọmọ Lefi ti tọ́jú ẹbọ ìrékọjá tiwọn fún wọn. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ìsìn Àjọ Ìrékọjá ati ti ẹbọ sísun lórí pẹpẹ OLUWA ní ọjọ́ náà gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Josaya ọba. Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wá ṣe àsè Àjọ Ìrékọjá, wọ́n sì ṣe Àjọ Àìwúkàrà fún ọjọ́ meje. Kò tíì sí irú àsè Àjọ Ìrékọjá bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli láti ìgbà ayé wolii Samuẹli. Kò sì tíì sí ọba kankan ní Israẹli tí ó tíì ṣe àsè Àjọ Ìrékọjá bí Josaya ti ṣe pẹlu àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, àwọn eniyan Juda, àwọn tí wọ́n wá láti Israẹli ati àwọn ará Jerusalẹmu. Ní ọdún kejidinlogun ìjọba Josaya ni wọ́n ṣe Àjọ Ìrékọjá yìí. Nígbà tí ó yá lẹ́yìn tí Josaya ti ṣe ètò inú tẹmpili tán, Neko, ọba Ijipti wá jagun ní Kakemiṣi, ní odò Yufurate. Josaya sì digun lọ bá a jà. Neko rán ikọ̀ sí Josaya pé, “Kí ló lè fa ìjà láàrin wa, ìwọ ọba Juda? Ìwọ kọ́ ni mo wá bá jà lákòókò yìí, orílẹ̀-èdè tí èmi pẹlu rẹ̀ ní ìjà ni mo wá bá jà. Ọlọrun ni ó sì sọ fún mi pé kí n má jáfara, má ṣe dojú ìjà kọ Ọlọrun, nítorí pé ó wà pẹlu mi; kí ó má ba à pa ọ́ run.” Ṣugbọn Josaya ṣe oríkunkun, ó paradà kí wọ́n má baà dá a mọ̀, ó lọ bá a jà. Kò fetí sí ọ̀rọ̀ Neko, tí Ọlọrun sọ, ó lọ bá Neko jà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Megido. Àwọn tafàtafà ta Josaya ọba ní ọfà, ó bá pe àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó sì sọ fún wọn pé, “Ẹ gbé mi kúrò lójú ogun, nítorí mo ti fara gbọgbẹ́, ọgbẹ́ náà sì pọ̀.” Nítorí náà, wọ́n gbé e kúrò ninu kẹ̀kẹ́ ogun tí ó wà tẹ́lẹ̀ sinu òmíràn, wọ́n sì gbé e lọ sí Jerusalẹmu. Ó kú, wọ́n sì sin ín sí ibojì àwọn baba rẹ̀. Gbogbo Juda ati Jerusalẹmu ṣe ọ̀fọ̀ rẹ̀. Wolii Jeremaya kọ orin arò fún Josaya ọba. Ó ti di àṣà ní Israẹli fún àwọn akọrin, lọkunrin ati lobinrin láti máa mẹ́nu ba Josaya nígbàkúùgbà tí wọ́n bá ń kọrin arò. Àkọsílẹ̀ gbogbo àwọn nǹkan yòókù tí Josaya ṣe ati iṣẹ́ rere rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin OLUWA, gbogbo ohun tí ó ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, wà ninu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli ati ti Juda. Àwọn ọmọ ilẹ̀ Juda bá fi Joahasi, ọmọ Josaya, jọba ní Jerusalẹmu lẹ́yìn baba rẹ̀. Joahasi jẹ́ ẹni ọdún mẹtalelogun nígbà tí ó jọba, ó wà lórí oyè fún oṣù mẹta. Ọba Ijipti ni ó lé e kúrò lórí oyè ní Jerusalẹmu, ó sì mú àwọn ọmọ Juda ní ipá láti máa san ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ati ìwọ̀n talẹnti wúrà kan, gẹ́gẹ́ bí ìṣákọ́lẹ̀. Neko, ọba Ijipti fi Eliakimu, arakunrin Joahasi jọba lórí Jerusalẹmu ati Juda, ó yí orúkọ rẹ̀ pada sí Jehoiakimu, ó sì mú Joahasi lọ sí Ijipti. Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni Jehoiakimu nígbà tí ó jọba. Ó wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkanla. Ohun tí ó ṣe burú lójú OLUWA Ọlọrun rẹ̀. Nebukadinesari, ọba Babiloni, gbógun tì í, ó sì fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè é, ó fà á lọ sí Babiloni. Nebukadinesari, ọba Babiloni, kó ninu àwọn ohun èlò ilé OLUWA lọ sí Babiloni, ó kó wọn sinu ààfin rẹ̀ ní Babiloni. Àkọsílẹ̀ gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoiakimu ṣe ati gbogbo ohun ìríra tí ó ṣe, ati àwọn àìdára rẹ̀ wà ninu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli ati ti Juda. Jehoiakini, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Jehoiakini jẹ́ ọmọ ọdún mẹjọ nígbà tí ó jọba. Ó wà lórí oyè fún oṣù mẹta ati ọjọ́ mẹ́wàá ní Jerusalẹmu. Ohun tí ó ṣe burú lójú OLUWA. Nígbà tí ọdún yípo, Nebukadinesari, ọba Babiloni ranṣẹ lọ mú un wá sí Babiloni pẹlu àwọn ohun èlò olówó iyebíye tí ó wà ninu ilé OLUWA. Ó sì fi Sedekaya, arakunrin rẹ̀ jọba ní Jerusalẹmu ati Juda. Ẹni ọdún mọkanlelogun ni Sedekaya nígbà tí ó jọba. Ó wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkanla. Ohun tí ó ṣe burú lójú OLUWA Ọlọrun rẹ̀, kò rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú wolii Jeremaya ẹni tí Ọlọrun rán sí i láti bá a sọ̀rọ̀. Sedekaya ṣọ̀tẹ̀ sí Nebukadinesari, bẹ́ẹ̀ sì ni Nebukadinesari ti fi ipá mú un búra ní orúkọ OLUWA pé kò ní ṣọ̀tẹ̀ sí òun. Ó ṣoríkunkun, ó sì kọ̀ láti yipada sí OLUWA Ọlọrun Israẹli. Bákan náà, àwọn alufaa tí wọ́n jẹ́ aṣaaju ati àwọn eniyan yòókù pàápàá ṣe aiṣootọ sí OLUWA, wọ́n tẹ̀lé ìwà ìríra àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká, wọ́n sì sọ ilé tí OLUWA ti yà sí mímọ́ ní Jerusalẹmu di aláìmọ́. OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn kò dẹ́kun láti máa rán wolii sí wọn, nítorí pé àánú àwọn eniyan rẹ̀ ati ibùgbé rẹ̀ ń ṣe é. Ṣugbọn, yẹ̀yẹ́ ni wọ́n ń fi àwọn iranṣẹ Ọlọrun ṣe. Wọn kò náání ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ń kẹ́gàn àwọn wolii rẹ̀ títí tí OLUWA fi bínú sí wọn, débi pé kò sí àtúnṣe. Ọlọrun mú kí ọba Kalidea gbógun tì wọ́n. Ọba náà fi idà pa àwọn ọdọmọkunrin Juda ninu tẹmpili, kò ṣàánú àwọn ọdọmọkunrin tabi wundia, tabi àwọn àgbà tabi arúgbó; gbogbo wọn ni Ọlọrun fi lé e lọ́wọ́. Ọba Babiloni kó gbogbo ohun èlò ilé OLUWA, ati ńláńlá, ati kéékèèké, ati àwọn ìṣúra tí ó wà níbẹ̀, ati àwọn tí wọ́n wà ní ààfin ati ti ilé àwọn ìjòyè; ó kó gbogbo wọn patapata lọ sí Babiloni. Wọ́n jó ilé OLUWA, wọ́n wó odi Jerusalẹmu, wọ́n jó ààfin ọba, wọ́n sì ba gbogbo nǹkan olówó iyebíye ibẹ̀ jẹ́. Nebukadinesari kó gbogbo àwọn tí wọ́n kù tí wọn kò pa lẹ́rú, ati àwọn ọmọ wọn. Ó kó wọn lọ sí Babiloni, wọ́n sì ń sin òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ títí di àkókò ìjọba Pasia; kí ohun tí OLUWA ti sọ láti ẹnu wolii Jeremaya lè ṣẹ, pé, “Ilẹ̀ náà yóo di ahoro fún aadọrin ọdún kí ó lè ní gbogbo ìsinmi tí ó yẹ kí ó ti ní, ṣugbọn tí kò ní.” Ní ọdún kinni ìjọba Kirusi, ọba Pasia, OLUWA mú ohun tí ó ti sọ láti ẹnu wolii Jeremaya ṣẹ. OLUWA fi sí Kirusi lọ́kàn, ó sì pàṣẹ jákèjádò ìjọba rẹ̀. Ó kọ àṣẹ náà sílẹ̀ báyìí pé: “Èmi Kirusi, ọba Pasia, ni mo pàṣẹ yìí pé, ‘OLUWA Ọlọrun ọ̀run ni ó fún mi ní ìjọba lórí gbogbo ayé, òun ni ó sì ti pàṣẹ fún mi pé kí n kọ́ ilé kan fún òun ní Jerusalẹmu ní ilẹ̀ Juda. Nítorí náà, gbogbo àwọn tí wọ́n bá jẹ́ tirẹ̀ lára yín, kí wọ́n lọ sibẹ, kí OLUWA Ọlọrun wọn wà pẹlu wọn.’ ” Ní ọdún kinni ìjọba Kirusi, ọba Pasia, kí àsọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu wolii Jeremaya lè ṣẹ, OLUWA fi sí Kirusi ọba lọ́kàn láti kéde yíká gbogbo ìjọba rẹ̀ ati láti ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ pé: “Èmi Kirusi, ọba Pasia kéde pé: OLUWA Ọlọrun ọ̀run ti fi gbogbo ìjọba ayé fún mi, ó sì ti pàṣẹ fún mi pé kí n kọ́ ilé kan fún òun ní Jerusalẹmu ní ilẹ̀ Juda. Kí Ọlọrun wà pẹlu àwọn tí wọ́n jẹ́ eniyan rẹ̀. Ẹ lọ sí Jerusalẹmu ní ilẹ̀ Juda, kí ẹ tún ilé OLUWA Ọlọrun Israẹli kọ́, nítorí òun ni Ọlọrun tí wọn ń sìn ní Jerusalẹmu. Ní gbogbo ibi tí àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ninu àwọn eniyan rẹ̀ ń gbé, kí àwọn aládùúgbò wọn fi fadaka, wúrà, dúkìá, ati ẹran ọ̀sìn ta wọ́n lọ́rẹ, yàtọ̀ sí ọrẹ àtinúwá fún ilé Ọlọrun.” Àwọn olórí ninu ìdílé ẹ̀yà Juda ati ẹ̀yà Bẹnjamini, ati àwọn alufaa, ati àwọn ọmọ Lefi sì dìde, pẹlu àwọn tí Ọlọrun ti fi sí lọ́kàn láti tún ilé OLUWA tí ó wà ní Jerusalẹmu kọ́. Àwọn aládùúgbò wọn fi ohun èlò fadaka ati ti wúrà, ati dúkìá, ati ẹran ọ̀sìn, ati àwọn nǹkan olówó iyebíye ràn wọ́n lọ́wọ́, yàtọ̀ sí àwọn ọrẹ àtinúwá. Kirusi ọba náà kó àwọn ohun èlò inú ilé OLUWA jáde, tí Nebukadinesari kó wá sinu àwọn ilé oriṣa rẹ̀, láti Jerusalẹmu. Kirusi ọba fún Mitiredati, akápò ìjọba rẹ̀ ní àṣẹ láti kó wọn síta, ó sì kà wọ́n ní ọ̀kọ̀ọ̀kan fún Ṣeṣibasari, olórí ẹ̀yà Juda. Iye àwọn nǹkan náà nìyí: Ẹgbẹrun kan (1,000) àwo wúrà, ẹgbẹrun kan (1,000) àwo fadaka, àwo turari mọkandinlọgbọn; ọgbọ̀n àwokòtò wúrà, ẹgbaa ó lé irinwo ati mẹ́wàá (2,410) àwo fadaka kéékèèké, ẹgbẹrun (1,000) oríṣìíríṣìí ohun èlò mìíràn. Àpapọ̀ àwọn ohun èlò wúrà ati fadaka yìí jẹ́ ẹẹdẹgbaata ó lé irinwo (5,400). Ṣeṣibasari kó wọn lọ́wọ́ bí àwọn tí wọn kúrò ní oko ẹrú Babiloni ti ń bọ̀ wá sí Jerusalẹmu. Àwọn ọmọ Juda wọnyi ni wọ́n pada dé láti oko ẹrú ní Babiloni, níbi tí Nebukadinesari, ọba Babiloni, kó wọn lẹ́rú lọ. Wọ́n pada sí Jerusalẹmu ati ilẹ̀ Juda, olukuluku pada sí ìlú rẹ̀. Àwọn olórí wọn ni: Serubabeli, Jeṣua, Nehemaya, Seraaya, Reelaya, Modekai, Biliṣani, Misipa, Bigifai, Rehumu ati Baana. Iye àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n pada láti oko ẹrú ní ìdílé ìdílé nìyí: Àwọn ọmọ Paroṣi jẹ́ ẹgbaa lé mejilelaadọsan-an (2,172) Àwọn ọmọ Ṣefataya jẹ́ ọọdunrun ó lé mejilelaadọrin (372) Àwọn ọmọ Ara jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin lé marundinlọgọrin (775) Àwọn ọmọ Pahati Moabu láti inú ìran Jeṣua ati Joabu jẹ́ ẹgbẹrinla lé mejila (2,812) Àwọn ọmọ Elamu jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹrinlelaadọta (1,254) Àwọn ọmọ Satu jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ó lé marundinlaadọta (945) Àwọn ọmọ Sakai jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé ọgọta (760) Àwọn ọmọ Bani jẹ́ ẹgbẹta ó lé mejilelogoji (642) Àwọn ọmọ Bebai jẹ́ ẹgbaata ó lé mẹtalelogun (623) Àwọn ọmọ Asigadi jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mejilelogun (1,222) Àwọn ọmọ Adonikamu jẹ́ ẹgbẹta ó lé mẹrindinlaadọrin (666) Àwọn ọmọ Bigifai jẹ́ ẹgbaa ó lé mẹrindinlọgọta (2,056) Àwọn ọmọ Adini jẹ́ irinwo ó lé mẹrinlelaadọta (454) Àwọn ọmọ Ateri láti inú ìran Hesekaya jẹ́ mejidinlọgọrun-un Àwọn ọmọ Besai jẹ́ ọọdunrun ó lé mẹtalelogun (323) Àwọn ọmọ Jora jẹ́ aadọfa ó lé meji (112) Àwọn ọmọ Haṣumu jẹ́ igba ó lé mẹtalelogun (223) Àwọn ọmọ Gibari jẹ́ marundinlọgọrun-un Àwọn ọmọ Bẹtilẹhẹmu jẹ́ mẹtalelọgọfa (123) Àwọn eniyan Netofa jẹ́ mẹrindinlọgọta Àwọn eniyan Anatoti jẹ́ mejidinlaadoje (128) Àwọn ọmọ Asimafeti jẹ́ mejilelogoji Àwọn ọmọ Kiriati Jearimu; Kefira ati Beeroti jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé mẹtalelogoji (743) Àwọn ọmọ Rama ati Geba jẹ́ ẹgbẹta ó lé mọkanlelogun (621) Àwọn ọmọ Mikimaṣi jẹ́ mejilelọgọfa (122) Àwọn eniyan Bẹtẹli ati Ai jẹ́ igba ó lé mẹtalelogun (223) Àwọn ọmọ Nebo jẹ́ mejilelaadọta Àwọn ọmọ Magibiṣi jẹ́ mẹrindinlọgọjọ (156) Àwọn ọmọ Elamu keji jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹrinlelaadọta (1,254) Àwọn ọmọ Harimu jẹ́ ọọdunrun ó lé ogún (320) Àwọn ọmọ Lodi, Hadidi ati Ono jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé mẹẹdọgbọn (725) Àwọn ọmọ Jẹriko jẹ́ ojilelọọdunrun ó lé marun-un (345) Àwọn ọmọ Senaa jẹ́ egbejidinlogun ó lé ọgbọ̀n (3,630) Iye àwọn alufaa tí wọ́n pada dé láti, oko ẹrú wọn nìwọ̀nyí: Àwọn ọmọ Jedaaya láti inú ìdílé Jeṣua jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ó lé mẹtalelaadọrin (973) Àwọn ọmọ Imeri jẹ́ ẹgbẹrun ó lé mejilelaadọta (1,052) Àwọn ọmọ Paṣuri jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹtadinlaadọta (1,247) Àwọn ọmọ Harimu jẹ́ ẹgbẹrun ó lé mẹtadinlogun (1,017) Iye àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n pada dé láti oko ẹrú nìwọ̀nyí: Àwọn ọmọ Jeṣua ati Kadimieli láti inú ìran Hodafaya jẹ́ mẹrinlelaadọrin Àwọn ọmọ Asafu tí wọ́n jẹ́ akọrin ní tẹmpili jẹ́ mejidinlaadoje (128) Iye àwọn ọmọ àwọn aṣọ́nà: àwọn ọmọ Ṣalumu ati àwọn ọmọ Ateri, àwọn ọmọ Talimoni ati àwọn ọmọ Akubu; àwọn ọmọ Hatita ati àwọn ọmọ Ṣobai jẹ́ mọkandínlogoje (139) Àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Siha, àwọn ọmọ Hasufa ati àwọn ọmọ Tabaoti; àwọn ọmọ Kerosi, àwọn ọmọ Siaha ati àwọn ọmọ Padoni; àwọn ọmọ Lebana, àwọn ọmọ Hagaba ati àwọn ọmọ Akubu; àwọn ọmọ Hagabu, àwọn ọmọ Ṣamlai ati àwọn ọmọ Hanani; àwọn ọmọ Gideli, àwọn ọmọ Gahari ati àwọn ọmọ Reaaya; àwọn ọmọ Resini, àwọn ọmọ Nekoda ati àwọn ọmọ Gasamu; àwọn ọmọ Usa, àwọn ọmọ Pasea, ati àwọn ọmọ Besai; àwọn ọmọ Asina, àwọn ọmọ Meuni, ati àwọn ọmọ Nefisimu; àwọn ọmọ Bakibuki, àwọn ọmọ Akufa, àwọn ọmọ Hahuri, àwọn ọmọ Basiluti, àwọn ọmọ Mehida, ati àwọn ọmọ Haṣa, àwọn ọmọ Bakosi, àwọn ọmọ Sisera, ati àwọn ọmọ Tema, àwọn ọmọ Nesaya ati àwọn ọmọ Hatifa. Àwọn ọmọ àwọn iranṣẹ Solomoni nìyí: àwọn ọmọ Sotai, àwọn ọmọ Hasofereti, ati àwọn ọmọ Peruda; àwọn ọmọ Jaala, àwọn ọmọ Dakoni, ati àwọn ọmọ Gideli; àwọn ọmọ Ṣefataya ati àwọn ọmọ Hatili, àwọn ọmọ Pokereti Hasebaimu ati àwọn ọmọ Ami. Àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili ati àwọn ọmọ àwọn iranṣẹ Solomoni jẹ́ irinwo ó dín mẹjọ (392). Àwọn kan wá láti Teli Mela, Teli Hariṣa, Kerubu, Adani ati Imeri tí wọn kò mọ ìdílé baba wọn tabi ìran wọn, yálà wọ́n jẹ́ ọmọ Israẹli tabi wọn kì í ṣe ọmọ Israẹli àwọn nìwọ̀nyí: Àwọn ọmọ Delaaya, àwọn ọmọ Tobaya, ati àwọn ọmọ Nekoda. Gbogbo wọn jẹ́ ọtalelẹgbẹta ó dín mẹjọ (652). Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ alufaa ninu wọn nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Habaya, àwọn ọmọ Hakosi, ati àwọn ọmọ Basilai (tí ó fẹ́ aya ninu ìdílé Basilai ará Gileadi, tí wọ́n sì ń fi orúkọ àna rẹ̀ pe àwọn ọmọ rẹ̀). Wọ́n wá orúkọ wọn ninu ìwé àkọsílẹ̀ tí a kọ ní ìdílé ìdílé, ṣugbọn wọn kò rí i. Nítorí náà a kà wọ́n kún aláìmọ́, a sì yọ wọ́n kúrò ninu iṣẹ́ alufaa. Gomina sọ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ ninu àwọn oúnjẹ mímọ́ jùlọ, títí tí wọn yóo fi rí alufaa kan tí ó lè lo Urimu ati Tumimu láti wádìí lọ́wọ́ OLUWA. Àpapọ̀ gbogbo àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú dé jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹgbaa, ó lé ọtalelọọdunrun (42,360). Láìka àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin wọn tí wọ́n jẹ́ ẹẹdẹgbaarin ó lé ojilelọọdunrun ó dín mẹta (7,337). Wọ́n sì tún ní igba (200) akọrin lọkunrin, ati lobinrin. Àwọn ohun ọ̀sìn tí wọ́n kó bọ̀ nìwọ̀nyí: ẹṣin wọn jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé mẹrindinlogoji (736) akọ mààlúù wọn jẹ́ igba ó lé marundinlaadọta (245) Ràkúnmí wọn jẹ́ irinwo ó lé marundinlogoji (435), kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn jẹ́ ẹgbaata ó lé okoolelẹẹdẹgbẹrin (6,720). Nígbà tí wọ́n dé ilé OLUWA ní Jerusalẹmu, díẹ̀ ninu àwọn olórí ìdílé náà fi ọrẹ àtinúwá sílẹ̀ láti tún ilé Ọlọrun kọ́ sí ààyè rẹ̀. Wọ́n ṣe gẹ́gẹ́ bí agbára wọn ti tó. Wọ́n fi ọọdunrun ó lé mejila (312) kilogiramu wúrà ẹgbẹsan (1,800) kilogiramu fadaka ati ọgọrun-un (100) ẹ̀wù alufaa, ṣe ẹ̀bùn fún ilé OLUWA. Àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi ati àwọn kan ninu àwọn eniyan náà ń gbé Jerusalẹmu ati agbègbè rẹ̀. Àwọn akọrin, àwọn aṣọ́nà ati àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili ń gbé àwọn ìlú tí ó wà nítòsí wọn, àwọn ọmọ Israẹli yòókù sì ń gbé àwọn ìlú wọn. Ní oṣù keje tí àwọn ọmọ Israẹli ti pada sí ìlú wọn, gbogbo wọn péjọ sí Jerusalẹmu. Jeṣua, ọmọ Josadaki pẹlu àwọn alufaa ẹgbẹ́ rẹ̀ ati Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, pẹlu àwọn ìbátan rẹ̀ tún pẹpẹ Ọlọrun Israẹli kọ́, kí wọ́n baà lè máa rú ẹbọ sísun lórí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin Mose, eniyan Ọlọrun. Wọ́n tẹ́ pẹpẹ náà sí ibi tí ó wà tẹ́lẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń bẹ̀rù àwọn eniyan ibẹ̀; wọ́n sì ń rú ẹbọ sísun sí OLUWA lórí rẹ̀ ní àràárọ̀ ati ní alaalẹ́. Wọ́n ṣe àjọ̀dún Àgọ́ Àjọ, wọ́n rú ìwọ̀n ẹbọ sísun tí a ti ṣe ìlànà sílẹ̀ fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn náà, wọ́n rú àwọn ẹbọ wọnyi: ẹbọ àtìgbà-dégbà, ẹbọ oṣù titun, gbogbo ẹbọ ọjọ́ àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀ fún OLUWA, ati ti àwọn tí wọ́n bá fẹ́ rú ẹbọ àtinúwá sí OLUWA. Láti ọjọ́ kinni oṣù keje ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí rú ẹbọ sísun sí OLUWA bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, wọn kò tíì fi ìpìlẹ̀ tẹmpili lélẹ̀. Wọ́n fi owó sílẹ̀ fún àwọn tí wọn ń gbẹ́ òkúta ati fún àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà. Wọ́n fún àwọn ará Sidoni ati àwọn ará Tire ní oúnjẹ, ohun mímu, ati òróró; wọ́n fi ṣe pàṣípààrọ̀ fún igi kedari láti ilẹ̀ Lẹbanoni. Wọ́n ní kí wọ́n kó àwọn igi náà wá sí Jọpa ní etí òkun fún wọn gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Kirusi, ọba Pasia pa. Ní oṣù keji ọdún keji tí wọ́n dé sí ilé Ọlọrun ní Jerusalẹmu ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà. Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, ati Jeṣua ọmọ Josadaki, ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ rẹ̀, pẹlu àwọn arakunrin wọn yòókù, àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn tí wọ́n ti ìgbèkùn pada sí Jerusalẹmu. Wọ́n yan àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ti tó ọmọ ogún ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, láti máa bojútó iṣẹ́ ilé OLUWA. Jeṣua ati àwọn ọmọ rẹ̀ pẹlu àwọn ìbátan rẹ̀, ati Kadimieli pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀, ati àwọn ọmọ Juda ń ṣe alabojuto àwọn tí wọn ń kọ́ ilé Ọlọrun pẹlu àwọn ọmọ Henadadi, ati àwọn Lefi pẹlu àwọn ọmọ wọn ati àwọn ìbátan wọn. Nígbà tí àwọn mọlémọlé bẹ̀rẹ̀ sí fi ìpìlẹ̀ ilé OLUWA lélẹ̀, àwọn alufaa gbé ẹ̀wù wọn wọ̀, wọ́n dúró pẹlu fèrè lọ́wọ́ wọn. Ìdílé Asafu, ẹ̀yà Lefi, ń lu kimbali wọn, wọ́n fí ń yin OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ètò tí Dafidi, ọba Israẹli, ti ṣe. Pẹlu orin ìyìn ati ìdúpẹ́ wọ́n ń kọrin sí OLUWA pẹlu ègbè rẹ̀ pé, “OLUWA ṣeun, ìfẹ́ rẹ̀ sí Israẹli dúró títí lae.” Gbogbo àwọn eniyan hó ìhó ìyìn sí OLUWA, nítorí pé wọ́n fi ìpìlẹ̀ ilé OLUWA lélẹ̀. Ṣugbọn ọpọlọpọ àwọn alufaa, àwọn ẹ̀yà Lefi, ati àwọn olórí ìdílé, àwọn àgbàlagbà tí wọ́n gbọ́njú mọ ilé OLUWA ti tẹ́lẹ̀ sọkún, wọ́n kígbe sókè nígbà tí wọ́n rí bí a ti ń fi ìpìlẹ̀ ilé OLUWA náà lélẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn mìíràn hó fún ayọ̀. Kò sí ẹni tí ó lè mọ ìyàtọ̀ láàrin ariwo ẹkún ati ti ayọ̀ nítorí pé, gbogbo wọn ń kígbe sókè, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn eniyan sì gbọ́ igbe wọn ní ọ̀nà jíjìn réré. Nígbà ti àwọn ọ̀tá Juda ati ti Bẹnjamini gbọ́ pé àwọn tí wọ́n ti ìgbèkùn dé ti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé OLUWA Ọlọrun Israẹli, wọ́n wá sọ́dọ̀ Serubabeli, ati sọ́dọ̀ àwọn baálé baálé, wọ́n wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á jọ kọ́ ọ nítorí ọ̀kan náà ni wá, Ọlọrun yín ni àwa náà ń sìn, a sì ti ń rúbọ sí i láti ìgbà ayé Esaradoni, ọba Asiria, tí ó mú wa wá síhìn-ín.” Ṣugbọn Serubabeli, Jeṣua, ati àwọn baálé baálé tí wọ́n ṣẹ́kù ní Israẹli dá wọn lóhùn pé, “A kò fẹ́ kí ẹ bá wa lọ́wọ́ sí kíkọ́ ilé OLUWA Ọlọrun wa. Àwa nìkan ni a óo kọ́ ọ gẹ́gẹ́ bí Kirusi, ọba Pasia, ti pa á láṣẹ fún wa.” Nígbà náà ni àwọn tí wọ́n ti ń gbé ilẹ̀ náà mú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá àwọn ará ilẹ̀ Juda, wọ́n sì dẹ́rùbà wọ́n, kí wọ́n má baà lè kọ́ tẹmpili náà. Wọ́n gba àwọn olùdámọ̀ràn èké tí wọ́n ń san owó fún láti da ìpinnu àwọn ará Juda rú ní gbogbo àkókò ìjọba Kirusi, ọba Pasia, títí di àkókò Dariusi, ọba Pasia. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Ahasu-erusi, àwọn kan kọ ìwé wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọn tí ń gbé Juda ati Jerusalẹmu. Ní àkókò ìjọba Atasasesi, ọba Pasia, ni àwọn wọnyi dìde: Biṣilamu, Mitiredati, Tabeeli ati àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn yòókù. Wọ́n kọ̀wé sí ọba Pasia ní èdè Aremia, wọ́n sì túmọ̀ rẹ̀. Rehumu, olórí ogun, ati Ṣimiṣai, akọ̀wé, ni wọ́n kọ ìwé ẹ̀sùn sí ọba Atasasesi, nípa Jerusalẹmu ní orúkọ àwọn mejeeji ati ti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tí wọ́n ṣẹ́kù pẹlu àwọn adájọ́, àwọn gomina ati àwọn ará Pasia, àwọn eniyan Ereki, àwọn ará Babiloni ati àwọn eniyan Susa, àwọn ará Elamu, pẹlu àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí Osinapari, alágbára ati ọlọ́lá, kó wá láti máa gbé àwọn ìlú Samaria ati àwọn agbègbè tí wọ́n wà ní òdìkejì odò. Ohun tí wọ́n kọ sinu ìwé náà nìyí: “Sí ọba Atasasesi, àwa iranṣẹ rẹ tí a wà ní agbègbè òdìkejì odò kí ọba. A fẹ́ kí ọba mọ̀ pé àwọn Juu tí wọ́n wá láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ wa ti lọ sí Jerusalẹmu, wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ sí tún ìlú burúkú náà, tí ó kún fún ọ̀tẹ̀ kọ́. Wọ́n ti mọ odi rẹ̀, wọ́n sì ti fẹ́rẹ̀ parí ìpìlẹ̀ rẹ̀. Kabiyesi, tí wọ́n bá fi lè kọ́ ìlú náà parí, tí wọ́n sì parí odi rẹ̀, wọn kò ní san owó ìṣákọ́lẹ̀ mọ́. Eléyìí yóo sì dín owó tí ń wọ àpò ọba kù. A kò lè rí ohun tí kò dára kí á má sọ nítorí pé abẹ́ rẹ ni a ti ń jẹ; nítorí náà ni a fi gbọdọ̀ sọ fún ọba. Ìmọ̀ràn wa ni pé, kí ọba pàṣẹ láti lọ wá àkọsílẹ̀ tí àwọn baba ńlá yín ti kọ. Ẹ óo rí i pé ìlú ọlọ̀tẹ̀ ni ìlú yìí. Láti ìgbà laelae ni wọ́n ti jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ sí àwọn ọba agbègbè wọn. Ìdí rẹ̀ nìyí tí wọ́n fi pa ìlú náà run. A fẹ́ tẹ̀ ẹ́ mọ́ ọba létí pé bí àwọn eniyan wọnyi bá kọ́ ìlú yìí tí wọ́n sì mọ odi rẹ̀, kò ní ku ilẹ̀ kankan mọ́ fún ọba ní agbègbè òdìkejì odò.” Ọba désì ìwé náà pada sí Rehumu, olórí ogun ati Ṣimiṣai, akọ̀wé, ati sí àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn yòókù tí wọn ń gbé Samaria ati agbègbè òdìkejì odò yòókù. Ó ní, “Mo ki yín. Wọ́n ka ìwé tí ẹ kọ sí wa, wọ́n sì túmọ̀ rẹ̀ níwájú mi. Mo pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe ìwádìí, a sì rí i pé láti ayébáyé ni ìlú yìí tí ń ṣọ̀tẹ̀ sí àwọn ọba wọn. Àwọn ọba alágbára ti jẹ ní Jerusalẹmu, wọ́n ti jọba lórí gbogbo agbègbè òdìkejì odò, wọ́n sì gba owó ìṣákọ́lẹ̀, owó bodè lọ́wọ́ àwọn eniyan. Nítorí náà, ẹ pàṣẹ pé kí wọ́n dáwọ́ iṣẹ́ náà dúró títí wọn yóo fi gbọ́ àṣẹ mìíràn láti ọ̀dọ̀ mi. Ẹ má ṣe fi iṣẹ́ náà jáfara, nítorí tí ẹ bá fi falẹ̀, ó lè pa ọba lára.” Lẹsẹkẹsẹ tí wọ́n ka ìwé ọba tán sí etígbọ̀ọ́ Rehumu ati Ṣimiṣai ati àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, Rehumu ati Ṣimiṣai yára lọ sí Jerusalẹmu pẹlu àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, wọn sì fi ipá dá iṣẹ́ náà dúró. Báyìí ni iṣẹ́ kíkọ́ ilé Ọlọrun ṣe dúró ní Jerusalẹmu títí di ọdún keji ìjọba Dariusi, ọba Pasia. Wolii Hagai ati wolii Sakaraya, ọmọ Ido, bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún àwọn Juu tí wọ́n wà ni Juda ati Jerusalẹmu ní orúkọ Ọlọrun Israẹli, ẹni tí ó jẹ́ orí fún wọn. Nígbà tí Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli ati Jeṣua, ọmọ Josadaki gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lórí àtikọ́ ilé Ọlọrun ní Jerusalẹmu, àwọn wolii Ọlọrun mejeeji sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Ní àkókò kan náà, Tatenai, gomina agbègbè òdìkejì odò ati Ṣetari Bosenai ati gbogbo àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn wá sí ọ̀dọ̀ wọn, wọ́n bi wọ́n léèrè pé: “Ta ló fun yín láṣẹ láti kọ́ tẹmpili yìí ati láti dá àwọn nǹkan inú rẹ̀ pada sibẹ? Ati pé, kí ni orúkọ àwọn tí wọ́n ń kọ́ ilé yìí?” Ṣugbọn Ọlọrun wà pẹlu àwọn olórí Juu, wọn kò sì lè dá wọn dúró títí tí wọn fi kọ̀wé sí Dariusi ọba, tí wọ́n sì rí èsì ìwé náà gbà. Ohun tí Tatenai ati Ṣetari Bosenai ati àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn kọ sinu ìwé sí Dariusi ọba nìyí: “Sí Dariusi ọba, kí ọba ó pẹ́. “A fẹ́ kí ọba mọ̀ pé, a lọ sí agbègbè Juda, a sì dé ilé tí wọ́n kọ́ fún Ọlọrun tí ó tóbi. Òkúta ńláńlá ni wọ́n fi ń kọ́ ọ, wọ́n sì ń tẹ́ pákó sára ògiri rẹ̀. Tọkàntọkàn ni wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ náà, ó sì ń tẹ̀síwájú. “A bèèrè lọ́wọ́ àwọn àgbààgbà wọn pé, ta ló fun wọn láṣẹ láti tún tẹmpili yìí kọ́ ati láti dá àwọn nǹkan inú rẹ̀ pada sibẹ. A bèèrè orúkọ wọn, kí á baà lè kọ orúkọ olórí wọn sílẹ̀ láti fi ranṣẹ sí kabiyesi. “Ìdáhùn tí wọ́n fún wa ni pé: ‘Iranṣẹ Ọlọrun ọ̀run ati ayé ni wá. Tẹmpili tí à ń tún kọ́ yìí, ọba olókìkí kan ni ó kọ́ ọ parí ní ọpọlọpọ ọdún sẹ́yìn. Ṣugbọn nítorí pé àwọn baba wa mú Ọlọrun ọ̀run bínú, ó fi wọ́n lé Nebukadinesari ọba Babiloni, ní ilẹ̀ Kalidea lọ́wọ́, òun ni ó wó tẹmpili yìí palẹ̀, tí ó sì kó àwọn eniyan ibẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Babilonia. Ṣugbọn ní ọdún kinni ìjọba Kirusi, ọba Babiloni, ó fi àṣẹ sí i pé kí wọ́n lọ tún tẹmpili náà kọ́. Ó dá àwọn ohun èlò wúrà ati ti fadaka pada, tí Nebukadinesari kó ninu ilé OLUWA ní Jerusalẹmu, lọ sí ilé oriṣa rẹ̀ ní Babiloni tẹ́lẹ̀. Gbogbo nǹkan wọnyi ni Kirusi ọba kó jáde kúrò ninu tẹmpili ní Babiloni, ó kó wọn lé Ṣeṣibasari lọ́wọ́, ẹni tí ó yàn ní gomina lórí Juda. Ó sọ fún un nígbà náà pé, “Gba àwọn ohun èèlò wọnyi, kó wọn lọ sinu tẹmpili tí ó wà ní Jerusalẹmu, kí ẹ sì tún tẹmpili náà kọ́ sí ojú ibi tí ó wà tẹ́lẹ̀.” Ṣeṣibasari bá wá, ó sì fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ ní Jerusalẹmu. Láti ìgbà náà ni iṣẹ́ ti ń lọ níbẹ̀ títí di ìsinsìnyìí, kò sì tíì parí.’ “Nítorí náà, kabiyesi, tí ó bá dára lójú rẹ, jẹ́ kí wọ́n lọ wo ìwé àkọsílẹ̀ ní Babiloni bí kìí bá ṣe nítòótọ́ ni Kirusi pàṣẹ pé kí wọ́n tún ilé Ọlọrun kọ́ ní Jerusalẹmu. Lẹ́yìn náà jẹ́ kí á mọ ohun tí o fẹ́ kí á ṣe nípa ọ̀rọ̀ yìí.” Dariusi ọba pàṣẹ pé kí wọ́n wádìí fínnífínní ninu àwọn ìwé àkọsílẹ̀ tí ó wà ní ààfin, ní ilẹ̀ Babiloni. Ṣugbọn ní ìlú Ekibatana, olú-ìlú tí ó wà ní agbègbè Media, ni wọ́n ti rí ìwé àkọsílẹ̀ kan tí ó kà báyìí pé: “Ní ọdún kinni ìjọba Kirusi ni ó pàṣẹ pé kí wọn tún ilé Ọlọrun tí ó wà ní Jerusalẹmu kọ́ fún ìrúbọ ati fún ọrẹ ẹbọ sísun. Gíga ilé Ọlọrun náà gbọdọ̀ jẹ́ ọgọta igbọnwọ, (mita 27), kí ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ọgọta igbọnwọ, (mita 27). Kí ògiri jẹ́ ìlè igi kan lórí ìlè òkúta mẹta. Ninu ilé ìṣúra ààfin ọba ni kí wọ́n ti mú owó kí wọ́n fi san owó iṣẹ́ náà. Gbogbo ohun èlò ìṣúra wúrà ati fadaka inú tẹmpili ní Jerusalẹmu, tí Nebukadinesari kó lọ sí Babiloni, ni kí wọ́n kó pada wá sí Jerusalẹmu, kí wọ́n sì fi wọ́n sí ààyè wọn ninu ilé Ọlọrun.” Nígbà náà ni Dariusi ọba désì ìwé Tatenai pada, ó ní, “Sí Tatenai, gomina agbègbè òdìkejì odò, ati Ṣetari Bosenai ati àwọn gomina ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n wà ní agbègbè òdìkejì odò. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀, ẹ má dí wọn lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ kí gomina Juda ati àwọn àgbààgbà Juu tún ilé Ọlọrun náà kọ́ síbi tí ó wà tẹ́lẹ̀. Ati pé, mo pàṣẹ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe láti ran àwọn àgbààgbà Juu lọ́wọ́ láti kọ́ ilé Ọlọrun náà pé: Ninu àpò ìṣúra ọba ati lára owó bodè ni kí ẹ ti mú, kí ẹ fi san gbogbo owó àwọn òṣìṣẹ́ ní àsanpé, kí iṣẹ́ lè máa lọ láìsí ìdádúró. Lojoojumọ, ni kí ẹ máa fún àwọn alufaa tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu ní iye akọ mààlúù, àgbò, aguntan pẹlu ìwọ̀n ọkà, iyọ̀, ọtí waini ati òróró olifi, tí wọn bá bèèrè fún ẹbọ sísun sí Ọlọrun ọ̀run. Kí wọ́n baà lè rú ẹbọ tí yóo jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà sí Ọlọrun ọ̀run, kí wọ́n sì lè máa gbadura ibukun fún èmi ati àwọn ọmọ mi. Siwaju sí i, mo tún pàṣẹ pé, bí ẹnikẹ́ni bá rú òfin mi yìí, kí wọ́n yọ ọ̀kan ninu igi òrùlé rẹ̀; kí wọ́n gbẹ́ ẹ ṣóńṣó, kí wọ́n tì í bọ̀ ọ́ láti ìdí títí dé orí rẹ̀. Kí wọ́n sì sọ ilé rẹ̀ di ààtàn. Kí Ọlọrun, tí ó yan Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí ibi ìsìn rẹ̀, pa ẹni náà run, kì báà ṣe ọba tabi orílẹ̀-èdè kan ni ó bá tàpá sí òfin yìí, tí ó sì ń wá ọ̀nà láti wó ilé Ọlọrun tí ó wà ní Jerusalẹmu. Èmi Dariusi ọba ni mo pa àṣẹ yìí, ẹ sì gbọdọ̀ mú un ṣẹ fínnífínní.” Tatenai, gomina, Ṣetari Bosenai ati àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tẹ̀lé gbogbo àṣẹ tí Dariusi ọba pa fún wọn lẹ́sẹẹsẹ. Àwọn àgbààgbà Juu ń kọ́ ilé náà, wọ́n sì ń ṣe àṣeyọrí pẹlu ìdálọ́kànle tí àsọtẹ́lẹ̀ tí wolii Hagai ati Sakaraya, ọmọ Ido ń fún wọn. Wọ́n parí kíkọ́ tẹmpili náà bí Ọlọrun Israẹli ti pa á láṣẹ fún wọn ati gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Kirusi, ati ti Dariusi ati ti Atasasesi, àwọn ọba Pasia. Wọ́n parí kíkọ́ Tẹmpili náà ní ọjọ́ kẹta oṣù Adari, ní ọdún kẹfa ìjọba Dariusi. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli: àwọn alufaa, àwọn ẹ̀yà Lefi ati àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú pada dé bá fi tayọ̀tayọ̀ ṣe ayẹyẹ ìyàsímímọ́ tẹmpili náà. Ọgọrun-un ọ̀dọ́ akọ mààlúù, igba (200) àgbò, ati irinwo (400) ọ̀dọ́ aguntan ni wọ́n fi rú ẹbọ ìyàsímímọ́ náà. Wọ́n sì fi ewúrẹ́ kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu ẹ̀yà Israẹli mejeejila. Wọ́n sì fi àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi sí ipò wọn ninu iṣẹ́ ìsìn inú Tẹmpili, ní Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí a ṣe kọ ọ́ sílẹ̀ ninu ìwé Mose. Ní ọjọ́ kẹrinla, oṣù kinni ọdún tí ó tẹ̀lé e, àwọn Juu tí wọ́n pada láti oko ẹrú ṣe ayẹyẹ Àjọ Ìrékọjá. Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi ya ara wọn sí mímọ́ lápapọ̀, fún ayẹyẹ náà. Wọ́n pa ọ̀dọ́ aguntan Àjọ Ìrékọjá fún àwọn tí wọ́n pada dé láti oko ẹrú, wọ́n pa fún àwọn alufaa ẹlẹgbẹ́ wọn, ati fún àwọn tìkara wọn. Gbogbo àwọn Juu tí wọ́n pada láti oko ẹrú ati àwọn tí wọ́n kọ ẹ̀sìn ìbọ̀rìṣà sílẹ̀ láti sin OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí wọn ń bá wọn gbé ní ilẹ̀ náà, tí wọ́n sì wá síbi ayẹyẹ náà pẹlu wọn, ni wọ́n jọ jẹ àsè náà. Ọjọ́ meje ni wọ́n fi fi tayọ̀tayọ̀ ṣe ayẹyẹ Àjọ Àìwúkàrà, nítorí pé Ọlọrun ti fún wọn ní ayọ̀ nítorí inú ọba Asiria tí ó yọ́ sí wọn, tí ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tún ilé Ọlọrun Israẹli kọ́. Lẹ́yìn náà, ní àkókò ìjọba Atasasesi, ọba Pasia, ọkunrin kan wà, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹsira, ọmọ Seraaya, ọmọ Asaraya, ọmọ Hilikaya, ọmọ Ṣalumu, ọmọ Sadoku, ọmọ Ahitubu, ọmọ Amaraya, ọmọ Asaraya, ọmọ Meraiotu, ọmọ Serahaya, ọmọ Usi, ọmọ Buki, ọmọ Abiṣua, ọmọ Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni, olórí alufaa. Láti Babiloni ni Ẹsira tí à ń wí yìí ti dé. Akọ̀wé ni, ó sì já fáfá ninu òfin Mose, tí OLUWA Ọlọrun Israẹli fún wọn. Ọba fún un ní gbogbo nǹkan tí ó bèèrè, nítorí pé ó rí ojurere OLUWA Ọlọrun rẹ̀. Ní ọdún keje ìjọba Atasasesi, díẹ̀ ninu àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ti ìgbèkùn dé: àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́nà ati àwọn iranṣẹ ninu Tẹmpili, wá sí Jerusalẹmu. Ní oṣù karun-un ọdún keje ìjọba Atasasesi ni Ẹsira dé sí Jerusalẹmu. Ó bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ̀ láti Babiloni ní ọjọ́ kinni oṣù kinni, ó sì dé Jerusalẹmu ní ọjọ́ kinni oṣù karun-un nítorí pé ó rí ojurere Ọlọrun. Nítorí Ẹsira fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sí kíkọ́ òfin OLUWA, ati pípa á mọ́ ati kíkọ́ gbogbo àwọn ọmọ Israẹli. Ohun tí wọ́n kọ sinu ìwé tí ọba Atasasesi fún Ẹsira nìyí, “Láti ọ̀dọ̀ Atasasesi ọba, sí Ẹsira, alufaa, tí ó tún jẹ́ akọ̀wé òfin Ọlọrun ọ̀run. “Mo pàṣẹ jákèjádò ìjọba mi pé bí ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli tabi àwọn alufaa, tabi àwọn ọmọ Lefi bá fẹ́ bá ọ pada lọ sí Jerusalẹmu, kí ó máa bá ọ lọ; nítorí pé èmi ati àwọn olùdámọ̀ràn mi meje ni a rán ọ lọ láti ṣe ìwádìí fínnífínní lórí Juda ati Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí òfin Ọlọrun rẹ tí ó wà lọ́wọ́ rẹ, ati pé kí o kó ọrẹ wúrà ati fadaka lọ́wọ́, tí ọba ati àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ fi ṣe ọrẹ àtinúwá fún Ọlọrun Israẹli, tí ibùgbé rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu. O níláti kó gbogbo wúrà ati fadaka tí o bá rí ní gbogbo agbègbè Babiloni, ati ọrẹ àtinúwá tí àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn alufaa bá fínnúfẹ́dọ̀ dá jọ fún Tẹmpili Ọlọrun wọn ní Jerusalẹmu. “Ṣíṣọ́ ni kí o ṣọ́ owó yìí ná: fi ra akọ mààlúù, àgbò, ati ọ̀dọ́ aguntan ati èròjà ẹbọ ohun jíjẹ ati ohun mímu, kí o fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ Tẹmpili Ọlọrun rẹ tí ó wà ní Jerusalẹmu. Fadaka ati wúrà tí ó bá ṣẹ́kù, ìwọ ati àwọn eniyan rẹ, ẹ lò ó bí ó ti yẹ lójú yín ati gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọrun yín. Gbogbo ohun èlò tí wọ́n kó fún ọ fún lílò ninu Tẹmpili Ọlọrun ni kí o kó lọ sí Jerusalẹmu, níwájú Ọlọrun. Bí o bá fẹ́ ohunkohun sí i fún lílò ninu Tẹmpili Ọlọrun rẹ, gbà á ninu ilé ìṣúra ọba. “Èmi Atasasesi ọba pàṣẹ fún àwọn olùtọ́jú ilé ìṣúra ní agbègbè òdìkejì odò láti pèsè gbogbo nǹkan tí Ẹsira, alufaa akọ̀wé òfin Ọlọrun ọ̀run, bá fẹ́ fún un. Ó láṣẹ láti gbà tó ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ọgọrun-un (100) òṣùnwọ̀n kori ọkà, ọgọrun-un (100) òṣùnwọ̀n bati ọtí waini, ọgọrun-un (100) òṣùnwọ̀n bati òróró, ati ìwọ̀n iyọ̀ tí ó bá fẹ́. Kí ẹ rí i pé ẹ tọ́jú gbogbo nǹkan tí Ọlọrun ọ̀run bá pa láṣẹ fún lílò ninu Tẹmpili rẹ̀, kí ibinu rẹ̀ má baà wá sórí ibùjókòó ọba ati àwọn ọmọ rẹ̀. A tún fi ń ye yín pé kò bá òfin mu láti gba owó ìṣákọ́lẹ̀, tabi owó bodè, tabi owó orí lọ́wọ́ àwọn alufaa, tabi àwọn ọmọ Lefi, tabi àwọn akọrin, tabi àwọn aṣọ́nà, tabi àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili, tabi àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn ninu ilé Ọlọrun. “Kí ìwọ Ẹsira, lo ọgbọ́n tí Ọlọrun rẹ fún ọ, kí o yan àwọn alákòóso ati àwọn adájọ́ tí wọ́n mọ òfin Ọlọrun rẹ, kí wọ́n lè máa ṣe ìdájọ́ àwọn tí wọ́n wà ní agbègbè òdìkejì odò. Kí o sì kọ́ àwọn tí kò mọ òfin Ọlọrun rẹ kí àwọn náà lè mọ̀ ọ́n. Ẹnikẹ́ni tí kò bá tẹríba fún òfin Ọlọrun rẹ ati àṣẹ ọba, pípa ni a óo pa á, tabi kí á wà á lọ kúrò ní ìlú, tabi kí á gba dúkìá rẹ̀, tabi kí á gbé e sọ sẹ́wọ̀n.” Ẹsira bá dáhùn pé, “Ìyìn ni fún OLUWA, Ọlọrun àwọn baba wa, tí ó fi sí ọba lọ́kàn láti ṣe ọ̀ṣọ́ sí tẹmpili Ọlọrun ní Jerusalẹmu, tí ó fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn mí níwájú ọba, pẹlu àwọn ìgbìmọ̀ ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ pataki pataki. Nítorí pé OLUWA Ọlọrun wà pẹlu mi, mo ṣe ọkàn gírí, mo kó àwọn aṣiwaju àwọn ọmọ Israẹli jọ, mo ní kí wọ́n bá mi kálọ.” Àkọsílẹ̀ àwọn eniyan ati àwọn baálé baálé tí wọ́n bá mi pada wá láti Babiloni ní àkókò Atasasesi, ọba, nìyí: Ninu àwọn ọmọ Finehasi, Geriṣomu ni olórí. Ninu àwọn ọmọ Itamari, Daniẹli ni olórí. Ninu àwọn ọmọ Dafidi, Hatuṣi, ọmọ Ṣekanaya, ni olórí. Ninu àwọn ọmọ Paroṣi, Sakaraya ni olórí; orúkọ aadọjọ (150) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀. Ninu àwọn ọmọ Pahati Moabu, Eliehoenai, ọmọ Serahaya, ni olórí; orúkọ igba (200) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀. Ninu àwọn ọmọ Satu, Ṣekanaya, ọmọ Jahasieli, ni olórí; orúkọ ọọdunrun (300) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀. Ninu àwọn ọmọ Adini, Ebedi, ọmọ Jonatani, ni olórí; orúkọ aadọta eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀. Ninu àwọn ọmọ Elamu, Jeṣaya, ọmọ Atalaya, ni olórí; orúkọ aadọrin eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀. Ninu àwọn ọmọ Ṣefataya, Sebadaya, ọmọ Mikaeli, ni olórí; orúkọ ọgọrin eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀. Ninu àwọn ọmọ Joabu, Ọbadaya, ọmọ Jehieli, ni olórí; orúkọ igba eniyan ó lé mejidinlogun (218) ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀. Ninu àwọn ọmọ Bani, Ṣelomiti, ọmọ Josifaya, ni olórí; orúkọ ọgọjọ (160) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀. Ninu àwọn ọmọ Bebai, Sakaraya, ọmọ Bebai, ni olórí; orúkọ eniyan mejidinlọgbọn ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀. Ninu àwọn ọmọ Asigadi, Johanani, ọmọ Hakatani, ni olórí; orúkọ aadọfa (110) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀. Ninu àwọn ọmọ Adonikamu, orúkọ àwọn tí wọ́n dé lẹ́yìn àwọn tí wọ́n kọ́ dé ni: Elifeleti, Jeueli ati Ṣemaaya; orúkọ ọgọta eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu wọn. Ninu àwọn ọmọ Bigifai, Utai ati Sakuri ni olórí, orúkọ aadọrin eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu wọn. Mo pe gbogbo wọn jọ síbi odò tí ń ṣàn lọ sí Ahafa, a sì pàgọ́ sibẹ fún ọjọ́ mẹta. Nígbà tí mo wo ààrin àwọn eniyan ati àwọn alufaa, n kò rí ọmọ Lefi kankan níbẹ̀. Mo bá ranṣẹ pe àwọn olórí wọn wọnyi: Elieseri, Arieli ati Ṣemaaya, Elinatani, Jaribu, Elinatani Natani, Sakaraya, ati Meṣulamu. Mo sì tún ranṣẹ pe Joiaribu ati Elinatani, tí wọ́n jẹ́ amòye. Mo rán wọn lọ sọ́dọ̀ Ido, olórí àwọn eniyan ní Kasifia; mo ní kí wọ́n sọ fún Ido ati àwọn arakunrin rẹ̀ tí ń ṣiṣẹ́ ninu tẹmpili pé kí wọ́n fi àwọn eniyan tí yóo máa ṣe iṣẹ́ ìsìn ninu ilé Ọlọrun wa ranṣẹ. Pẹlu ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun, wọ́n fi Ṣerebaya, ọlọ́gbọ́n eniyan kan ranṣẹ sí wa. Ọmọ Israẹli ni, láti inú àwọn ọmọ Mahili, ninu ẹ̀yà Lefi: wọ́n fi ranṣẹ pẹlu àwọn ọmọ ati àwọn arakunrin rẹ̀. Gbogbo wọn jẹ́ mejidinlogun. Wọ́n tún rán Haṣabaya, òun ati Jeṣaya ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Merari; pẹlu àwọn arakunrin rẹ̀, ati àwọn ọmọ wọn. Gbogbo wọn jẹ́ ogún, láì tíì ka igba ó lé ogún (220) àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili, tí Dafidi ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ti yà sọ́tọ̀ láti máa ran àwọn ọmọ Lefi lọ́wọ́. Gbogbo wọn ni a kọ orúkọ wọn sinu ìwé. Lẹ́yìn náà, mo pàṣẹ létí odò Ahafa pé kí á gbààwẹ̀, kí á lè rẹ ara wa sílẹ̀ níwájú Ọlọrun wa, kí á sì bèèrè ìtọ́sọ́nà fún ara wa ati àwọn ọmọ wa, ati gbogbo ohun ìní wa. Ìtìjú ni ó jẹ́ fún mi láti bèèrè fún ọ̀wọ́ ọmọ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin tí yóo dáàbò bò wá ninu ìrìn àjò wa, nítorí mo ti sọ fún ọba pé Ọlọrun wa a máa ṣe rere fún àwọn tí wọ́n bá ń gbọ́ tirẹ̀; Ṣugbọn a máa fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí wọn kò bá tẹ̀lé e. Nítorí náà, a gba ààwẹ̀, a sì gbadura sí Ọlọ́run, ó sì gbọ́ tiwa. Lẹ́yìn náà mo ya àwọn àgbààgbà alufaa mejila sọ́tọ̀: Ṣerebaya, Haṣabaya ati mẹ́wàá ninu àwọn arakunrin wọn. Mo wọn fadaka, wúrà ati àwọn ohun èlò tí ọba, ati àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀, ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ mú wá, ati èyí tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà níbẹ̀ náà mú wá fún ìlò ilé Ọlọrun. Mo wọn ẹgbẹta lé aadọta (650) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ohun èlò fadaka tí a wọ̀n tó ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti wúrà, ogún àwo wúrà tí wọ́n tó ẹgbẹrun (1000) ìwọ̀n diramu ati ohun èlò idẹ meji tí ó ń dán, tí ó sì níye lórí bíi wúrà. Mo sọ fún wọn pé, “A yà yín ati gbogbo nǹkan wọnyi sí mímọ́ fún OLUWA. Fadaka ati wúrà jẹ́ ọrẹ àtinúwá fún OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín. Ẹ máa tọ́jú wọn kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́ títí tí ẹ óo fi wọ̀n wọ́n níwájú àwọn olórí alufaa, àwọn ọmọ Lefi ati àwọn baálé baálé Israẹli ní Jerusalẹmu ninu yàrá ilé OLUWA.” Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi gba fadaka, wúrà ati àwọn ohun èlò náà, wọ́n kó wọn wá sinu ilé Ọlọrun wa ní Jerusalẹmu. Ní ọjọ́ kejila oṣù kinni ni a kúrò ní odò Ahafa à ń bọ̀ wá sí Jerusalẹmu. Ọlọrun wà pẹlu wa, ó dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá ati àwọn dánàdánà. Nígbà tí a dé Jerusalẹmu a wà níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹta. Ní ọjọ́ kẹrin, a gbéra, a lọ sí ilé Ọlọrun, a wọn fadaka, wúrà ati àwọn ohun èlò, a sì kó wọn lé Meremoti, alufaa, ọmọ Uraya lọ́wọ́. Àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ níbẹ̀ ni Eleasari, ọmọ Finehasi, pẹlu àwọn ọmọ Lefi, Josabadi, ọmọ Jeṣua, ati Noadaya, ọmọ Binui. A ka gbogbo wọn, a sì ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí ìwọ̀n ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́. Àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú dé fi akọ mààlúù mejila rú ọrẹ ẹbọ sísun sí Ọlọrun Israẹli fún ẹ̀yà Israẹli mejila, pẹlu àgbò mẹrindinlọgọrun-un, ọ̀dọ́ aguntan mẹtadinlọgọrun-un, ati òbúkọ mejila fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Gbogbo àwọn ẹran wọnyi jẹ́ ẹbọ sísun fún Ọlọrun. Wọ́n fún àwọn aláṣẹ ati àwọn gomina tí ọba yàn fún àwọn ìgbèríko tí wọ́n wà ní òdìkejì odò ní ìwé àṣẹ tí ọba pa; àwọn aláṣẹ náà sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn ati fún iṣẹ́ ilé Ọlọrun. Lẹ́yìn nǹkan wọnyi, àwọn olórí àwọn ọmọ Israẹli wá sọ́dọ̀ mi, wọ́n ní: “Àwọn ọmọ Israẹli pẹlu àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi kò ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò ninu ìwà ìríra àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Hiti, ti àwọn ará Perisi ati àwọn ará Jebusi, ti àwọn ará Amoni ati àwọn ará Moabu, àwọn ará Ijipti, ati àwọn ará Amori. Wọ́n ń fẹ́ ọmọ lọ́wọ́ wọn fún ara wọn ati fún àwọn ọmọ wọn; àwọn ẹ̀yà mímọ́ sì ti darapọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká. Àwọn tí wọ́n jẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà jù ni àwọn olórí ati àwọn eniyan pataki ní Israẹli.” Nígbà tí mo gbọ́ bẹ́ẹ̀, mo fa aṣọ ati agbádá mi ya, láti fi ìbànújẹ́ mi hàn, mo sì fa irun orí ati irùngbọ̀n mi tu; mo sì jókòó pẹlu ìbànújẹ́. Mo jókòó bẹ́ẹ̀ títí di àkókò ẹbọ àṣáálẹ́. Gbogbo àwọn tí wọ́n bẹ̀rù ọ̀rọ̀ Ọlọrun rọ̀gbà yí mi ká nítorí aiṣootọ àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú dé. Ní àkókò ẹbọ àṣáálẹ́, mo dìde kúrò níbi tí mo ti ń gbààwẹ̀ pẹlu aṣọ ati agbádá mi tí ó ya, mo kúnlẹ̀, mo sì tẹ́wọ́ sí OLUWA Ọlọrun mi, mo gbadura pé: “Ọlọrun mi, ojú tì mí tóbẹ́ẹ̀ tí n kò lè gbójú sókè níwájú rẹ. Ìwà burúkú wa pọ̀ pupọ níwájú rẹ, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa ní ìpele ìpele, sì ga títí kan ọ̀run. Láti ayé àwọn baba wa títí di ìsinsìnyìí, ni àwa eniyan rẹ ti ń dẹ́ṣẹ̀ lọpọlọpọ. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, àwọn ọba ati àwọn alufaa wa ti bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọba ilẹ̀ àjèjì; wọ́n pa wá, wọ́n dè wá ní ìgbèkùn, wọ́n sì kó wa lẹ́rù. A wá di ẹni ẹ̀gàn títí di òní. Ṣugbọn fún ìgbà díẹ̀ ní àkókò yìí, OLUWA Ọlọrun wa, o ṣàánú wa, o dá díẹ̀ sí ninu wa, à ń gbé ní àìléwu ní ibi mímọ́ rẹ. O jẹ́ kí ara dẹ̀ wá díẹ̀ ní oko ẹrú, o sì ń mú inú wa dùn. Ẹrú ni wá; sibẹ ìwọ Ọlọrun wa kò fi wá sílẹ̀ ninu oko ẹrú, ṣugbọn o fi ìfẹ́ ńlá rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí wa, lọ́dọ̀ àwọn ọba Pasia; o sọ wá jí láti kọ́ ilé Ọlọrun wa, láti tún àwọn àlàpà rẹ̀ mọ ati láti mọ odi yí Judia ati Jerusalẹmu ká. “Áà, Ọlọrun wa, kí ni a tún lè wí lẹ́yìn èyí? Nítorí a ti kọ òfin rẹ sílẹ̀, àní, òfin tí o ṣe, tí o fi rán àwọn wolii sí wa pé, ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà yìí jẹ́ ilẹ̀ tí ó kún fún ẹ̀gbin ati ohun ìríra, pẹlu ìwà ẹ̀gbin àwọn eniyan jákèjádò ilẹ̀ náà ti sọ ọ́ di aláìmọ́. Nítorí náà, ẹ má fi àwọn ọmọbinrin yín fún àwọn ọmọkunrin wọn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ fẹ́ àwọn ọmọbinrin wọn fún àwọn ọmọkunrin yín. Ẹ kò gbọdọ̀ wá ire wọn tabi alaafia, kí ẹ lè lágbára, kí ẹ lè jẹ èrè ilẹ̀ náà, kí ó sì lè jẹ́ ohun ìní fún àwọn ìran yín títí lae. Lẹ́yìn gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa, nítorí ìwà burúkú wa ati ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tí a dá, a rí i pé ìyà tí ìwọ Ọlọrun fi jẹ wá kéré sí ẹ̀ṣẹ̀ wa; o jẹ́ kí àwa tí a pọ̀ tó báyìí ṣẹ́kù sílẹ̀. Ǹjẹ́ àwa tí a ṣẹ́kù yìí tún gbọdọ̀ máa rú òfin rẹ, kí á máa fẹ́ aya láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ń ṣe ohun ìríra? Ǹjẹ́ o kò ní bínú sí wa tóbẹ́ẹ̀ tí o óo fi pa wá run, tí a kò fi ní ṣẹ́ku ẹyọ ẹnìkan mọ́ tabi kí ẹyọ ẹnìkan sá àsálà? OLUWA Ọlọrun Israẹli, olódodo ni ọ́, nítorí díẹ̀ ninu wa ṣẹ́kù tí a sá àsálà títí di òní yìí. A wà níwájú rẹ báyìí pẹlu ẹ̀ṣẹ̀ wa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹni tí ó lè dúró níwájú rẹ báyìí.” Bí Ẹsira ti ń gbadura, tí ó ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, tí ó ń sọkún, tí ó sì dojúbolẹ̀ níwájú ilé Ọlọrun, àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí dúró yí i ká, tọmọde, tàgbà, tọkunrin, tobinrin. Àwọn náà ń sọkún gan-an. Ṣekanaya, ọmọ Jehieli, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Elamu bá sọ fún Ẹsira pé: “A ti hùwà ọ̀dàlẹ̀ sí Ọlọrun wa, nítorí a ti lọ fẹ́ aya láàrin àwọn ẹ̀yà tí wọ́n yí wa ká, sibẹsibẹ, ìrètí ń bẹ fún àwọn ọmọ Israẹli. Nítorí náà, jẹ́ kí á bá Ọlọrun wa dá majẹmu pé a óo lé àwọn obinrin àjèjì wọnyi lọ pẹlu àwọn ọmọ wọn gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwọ, oluwa mi, ati àwọn tí wọ́n bẹ̀rù òfin Ọlọrun wa wí, kí á ṣe é bí òfin ti wí. Ọwọ́ rẹ ni ọ̀rọ̀ yí wà; dìde nílẹ̀ kí o ṣe é. A wà lẹ́yìn rẹ, nítorí náà ṣe ọkàn gírí.” Ẹsira bá dìde nílẹ̀, ó wí fún gbogbo àwọn olórí alufaa, ati àwọn ọmọ Lefi, ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n búra pé wọn yóo ṣe gẹ́gẹ́ bí Ṣekanaya ti sọ, wọ́n sì búra. Nígbà náà ni Ẹsira kúrò níwájú ilé Ọlọrun, ó lọ sí yàrá Jehohanani, ọmọ Eliaṣibu, ibẹ̀ ni ó sùn ní alẹ́ ọjọ́ náà. Kò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò mu nítorí pé ó ń banújẹ́ nítorí aiṣootọ àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú pada dé. Wọ́n kéde jákèjádò Juda ati Jerusalẹmu pé kí gbogbo àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú pada dé péjọ sí Jerusalẹmu. Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ àwọn olórí ati àwọn àgbààgbà, ẹnikẹ́ni tí kò bá farahàn títí ọjọ́ mẹta, yóo pàdánù àwọn ohun ìní rẹ̀, a óo sì yọ ọ́ kúrò láàrin àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú dé. Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ kẹta yóo fi ṣú, gbogbo àwọn ọkunrin tí wọn ń gbé agbègbè Bẹnjamini ati Juda ni wọ́n wá sí Jerusalẹmu. Ní ogúnjọ́ oṣù kẹsan-an ni gbogbo wọn péjọ, wọn jókòó sí ìta gbangba níwájú ilé Ọlọrun. Gbogbo wọn ń gbọ̀n nítorí ọ̀rọ̀ tí wọ́n pè wọ́n fún ati nítorí òjò tí ń rọ̀. Ẹsira, alufaa, bá dìde, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ ti ṣẹ̀ níti pé ẹ fẹ́ obinrin àjèjì, ẹ sì ti mú kí ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli pọ̀ sí i. Nítorí náà ẹ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín fún OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín, kí ẹ sì máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan náà ati kúrò lọ́dọ̀ àwọn obinrin àjèjì.” Gbogbo àwọn eniyan náà kígbe sókè, wọ́n dáhùn pé, “Òtítọ́ ni o sọ, bí o ti wí ni a gbọdọ̀ ṣe. Ṣugbọn àwọn eniyan wọnyi pọ̀, ati pé àkókò òjò nìyí; a kò lè dúró ní gbangba báyìí. Ọ̀rọ̀ yìí kì í ṣe ohun tí a lè parí ní ọjọ́ kan tabi ọjọ́ meji, nítorí ohun tí a ṣe yìí, a ti ṣẹ̀ gan-an Jẹ́ kí àwọn olórí wa dúró fún gbogbo àwùjọ yìí, kí wọ́n dá ọjọ́ tí àwọn tí wọ́n fẹ́ iyawo àjèjì ninu àwọn ìlú wa yóo wá, pẹlu àwọn àgbààgbà, ati àwọn adájọ́ ìlú kọ̀ọ̀kan, títí ibinu Ọlọrun lórí ọ̀rọ̀ yìí yóo fi kúrò lórí wa.” Gbogbo wọn ni wọ́n faramọ́ ìmọ̀ràn yìí àfi Jonatani, ọmọ Asaheli ati Jahiseaya, ọmọ Tikifa. Àwọn ọmọ Lefi meji: Meṣulamu ati Ṣabetai náà faramọ́ àwọn tí wọ́n lòdì sí i. Àwọn tí wọ́n pada ti oko ẹrú dé gba ìmọ̀ràn yìí. Nítorí náà, Ẹsira alufaa yan àwọn olórí ninu ìdílé wọn, wọ́n kọ orúkọ wọn sílẹ̀. Ní ọjọ́ kinni oṣù kẹwaa, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìwádìí lórí ọ̀rọ̀ yìí. Nígbà tí yóo fi di ọjọ́ kinni oṣù kinni, wọ́n ti parí ìwádìí lórí gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ obinrin àjèjì. Orúkọ àwọn alufaa tí wọ́n fẹ́ àwọn obinrin àjèjì nìwọ̀nyí: Ninu ìdílé Jeṣua ọmọ Josadaki ati àwọn arakunrin rẹ̀: Maaseaya ati Elieseri, Jaribu, ati Gedalaya. Wọ́n ṣe ìpinnu láti kọ àwọn aya wọn sílẹ̀, wọ́n sì fi àgbò kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ninu ìdílé Imeri: Hanani, ati Sebadaya. Ninu ìdílé Harimu: Maaseaya, Elija, Ṣemaaya, Jehieli, ati Usaya. Ninu ìdílé Paṣuri: Elioenai, Maaseaya, Iṣimaeli, Netaneli, Josabadi, ati Elasa. Orúkọ àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n fẹ́ àwọn obinrin àjèjì nìwọ̀nyí: Josabadi, Ṣimei, Kelaya, (tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Kelita), Petahaya, Juda, ati Elieseri. Ninu àwọn akọrin, Eliaṣibu nìkan ni ó fẹ́ obinrin àjèjì. Orúkọ àwọn aṣọ́nà tí wọ́n fẹ́ obinrin àjèjì nìwọ̀nyí: Ṣalumu, Telemu, ati Uri. Orúkọ àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n fẹ́ obinrin àjèjì nìwọ̀nyí: Ninu ìdílé Paroṣi: Ramaya, Isaya, ati Malikija; Mijamini, Eleasari, Haṣabaya ati Benaaya. Ninu ìdílé Elamu: Matanaya, Sakaraya, ati Jehieli; Abidi, Jeremotu, ati Elija. Ninu ìdílé Satu: Elioenai, Eliaṣibu, ati Matanaya, Jeremotu, Sabadi, ati Asisa. Ninu ìdílé Bebai: Jehohanani, Hananaya, Sabai, ati Atilai. Ninu ìdílé Bani: Meṣulamu, Maluki, ati Adaaya, Jaṣubu, Ṣeali, ati Jeremotu. Ninu ìdílé Pahati Moabu: Adina, Kelali, ati Benaaya; Maaseaya, Matanaya, ati Besaleli; Binui, ati Manase. Ninu ìdílé Harimu: Elieseri, Iṣija, ati Malikija; Ṣemaaya, ati Ṣimeoni. Bẹnjamini, Maluki ati Ṣemaraya. Ninu ìdílé Haṣumu: Matenai, Matata, ati Sabadi; Elifeleti, Jeremai, Manase, ati Ṣimei. Ninu ìdílé Bani: Maadai, Amramu, ati Ueli; Benaaya, Bedeaya, ati Keluhi; Faniya, Meremoti, ati Eliaṣibu, Matanaya, Matenai ati Jaasu. Ninu ìdílé Binui: Ṣimei, Ṣelemaya, Natani, ati Adaaya, Makinadebai, Ṣaṣai ati Ṣarai, Asareli, Ṣelemaya, ati Ṣemaraya, Ṣalumu, Amaraya, ati Josẹfu. Ninu ìdílé Nebo: Jeieli, Matitaya, Sabadi, Sebina, Jadai, Joẹli, ati Benaaya. Gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ obinrin àjèjì ni wọ́n kọ àwọn aya wọn sílẹ̀ tọmọtọmọ. Ìtàn Nehemaya ọmọ Hakalaya. Ní oṣù Kisilefi, ní ogún ọdún tí Atasasesi jọba ní ilẹ̀ Pasia, mo wà ní Susa tíí ṣe olú-ìlú ilẹ̀ náà, Hanani, ọ̀kan ninu àwọn arakunrin mi, pẹlu àwọn kan tọ̀ mí wá láti ilẹ̀ Juda, mo bá bèèrè àwọn Juu tí wọ́n ṣẹ́kù, tí wọn kò kó lọ sóko ẹrú, mo sì tún bèèrè nípa Jerusalẹmu. Wọ́n sọ fún mi pé, “Inú wahala ńlá ati ìtìjú ni àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù, tí wọn kò kó lẹ́rú wà, ati pé odi Jerusalẹmu ti wó lulẹ̀, iná sì ti jó gbogbo ẹnu ọ̀nà rẹ̀.” Nígbà tí mo gbọ́ bẹ́ẹ̀, mo jókòó, mo sọkún, mo sì kẹ́dùn fún ọpọlọpọ ọjọ́. Mo bá bẹ̀rẹ̀ sí gbààwẹ̀, mo sì ń gbadura sí Ọlọrun ọ̀run pé, “OLUWA Ọlọrun ọ̀run, Ọlọrun tí ó tóbi tí ó sì lẹ́rù, Ọlọrun tíí máa pa majẹmu ati ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ mọ́ pẹlu àwọn tí wọ́n bá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́, tẹ́tí sílẹ̀, bojú wò mí, kí o sì fetí sí adura èmi iranṣẹ rẹ, tí mò ń gbà tọ̀sán-tòru nítorí àwọn ọmọ Israẹli, iranṣẹ rẹ, tí mo sì ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí a ṣẹ̀ ọ́. Wò ó, èmi ati ìdílé baba mi ti dẹ́ṣẹ̀. A ti hùwà burúkú sí ọ, a kò sì pa àwọn òfin, ati ìlànà ati àṣẹ rẹ tí o pa fún Mose iranṣẹ rẹ mọ́. Ranti ìlérí tí o ṣe fún Mose, iranṣẹ rẹ, pé, ‘Bí ẹ kò bá jẹ́ olóòótọ́, n óo fọn yín káàkiri sáàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, ṣugbọn tí ẹ bá pada sọ́dọ̀ mi, tí ẹ pa òfin mi mọ́, tí ẹ sì ń tẹ̀lé e, bí ẹ tilẹ̀ fọ́nká lọ sí ọ̀nà jíjìn réré, n óo ṣà yín jọ, n óo sì ko yín pada sí ibi tí mo ti yàn pé ẹ óo ti máa sìn mí kí orúkọ mi lè máa wà níbẹ̀.’ “Iranṣẹ rẹ ni wọ́n, eniyan rẹ sì ni wọ́n, àwọn tí o ti fi ipá ati agbára ọwọ́ rẹ rà pada. OLUWA, tẹ́tí sí adura èmi iranṣẹ rẹ, tí mo bẹ̀rù orúkọ rẹ, kí o sì jẹ́ kí n ṣe àṣeyọrí lónìí, kí n sì rí ojurere ọba.” Èmi ni agbọ́tí ọba ní àkókò náà. Ní oṣù Nisani, ní ogún ọdún tí Atasasesi ọba gorí oyè, mo gbé ọtí waini tí ó wà níwájú rẹ̀ fún un. N kò fajúro níwájú rẹ̀ rí. Nítorí náà, ọba bi mí léèrè pé, “Kí ló dé tí o fi fajúro? Ó dájú pé kò rẹ̀ ọ́. Ó níláti jẹ́ pé ọkàn rẹ bàjẹ́ ni.” Ẹ̀rù bà mí pupọ. Mo bá dá ọba lóhùn pé, “Kí ẹ̀mí ọba gùn! Báwo ni ojú mi kò ṣe ní fàro, nígbà tí ìlú tí ibojì àwọn baba mi wà, ti di ahoro, tí iná sì ti jó àwọn ẹnubodè rẹ̀?” Ọba bá bèèrè lọ́wọ́ mi pé, “Kí ni ohun tí o wá fẹ́?” Nítorí náà, mo gbadura sí Ọlọrun ọ̀run. Mo bá sọ fún ọba pé, “Bí ó bá tẹ́ kabiyesi lọ́rùn, tí èmi iranṣẹ rẹ bá sì rí ojurere rẹ, rán mi lọ sí Juda, ní ìlú tí ibojì àwọn baba mi wà, kí n lọ tún ìlú náà kọ́.” Ayaba wà ní ìjókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọba, ọba bá bèèrè lọ́wọ́ mi pé, “O óo lò tó ọjọ́ mélòó lọ́hùn-ún? Ìgbà wo ni o sì fẹ́ pada?” Inú ọba dùn láti rán mi lọ, èmi náà sì dá ìgbà fún un. Mo fún ọba lésì pé, “Bí ó bá tẹ́ kabiyesi lọ́rùn bẹ́ẹ̀, kí kabiyesi kọ̀wé lé mi lọ́wọ́ kí n lọ fún àwọn gomina ìgbèríko òdìkejì odò, kí wọ́n lè jẹ́ kí n rékọjá lọ sí Juda, kí ó kọ ìwé sí Asafu, olùṣọ́ igbó ọba, kí ó fún mi ní igi kí n fi ṣe odi ẹnu ọ̀nà tẹmpili, ati ti odi ìlú, ati èyí tí n óo fi kọ́ ilé tí n óo máa gbé.” Ọba ṣe gbogbo ohun tí mo bèèrè fún mi, nítorí pé Ọlọrun lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ mi. Mo bá tọ àwọn gomina ìgbèríko òdìkejì odò lọ mo fún wọn ní lẹta tí ọba kọ. Ọba rán àwọn olórí ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin tẹ̀lé mi. Ṣugbọn nígbà tí Sanbalati ará Horoni ati Tobaya iranṣẹ ọba, ará Amoni gbọ́, inú bí wọn pé ẹnìkan lè máa wá alaafia àwọn ọmọ Israẹli. Mo bá wá sí Jerusalẹmu mo sì wà níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹta. Mo gbéra ní alẹ́ èmi ati àwọn eniyan díẹ̀, ṣugbọn n kò sọ ohun tí Ọlọrun mi fi sí mi lọ́kàn láti ṣe ní Jerusalẹmu fún ẹnikẹ́ni. Kò sí ẹranko kankan pẹlu mi àfi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí mo gùn. Mo gbéra lóru, mo gba Ẹnubodè Àfonífojì. Mo jáde sí kànga Diragoni, mo gba ibẹ̀ lọ sí Ẹnubodè Ààtàn. Bí mo ti ń lọ, mò ń wo àwọn ògiri Jerusalẹmu tí wọ́n ti wó lulẹ̀ ati àwọn ẹnu ọ̀nà tí wọ́n ti jó níná. Lẹ́yìn náà, mo lọ sí Ẹnubodè Orísun ati ibi Adágún ọba, ṣugbọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí mo gùn kò rí ọ̀nà kọjá. Lóru náà ni mo gba àfonífojì Kidironi gòkè lọ, mo sì ṣe àyẹ̀wò odi náà yíká, lẹ́yìn náà, mo pẹ̀yìndà mo sì gba Ẹnubodè Àfonífojì wọlé pada. Àwọn ìjòyè náà kò sì mọ ibi tí mo lọ tabi ohun tí mo lọ ṣe, n kò sì tíì sọ nǹkankan fún àwọn Juu, ẹlẹgbẹ́ mi: àwọn alufaa, ati àwọn ọlọ́lá, tabi àwọn ìjòyè ati àwọn yòókù tí wọn yóo jọ ṣe iṣẹ́ náà. Lẹ́yìn náà, mo sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí irú ìyọnu tí ó dé bá wa! Ẹ wò ó bí Jerusalẹmu ṣe parun tí àwọn ẹnu ọ̀nà rẹ̀ sì jóná. Ẹ múra, ẹ jẹ́ kí á kọ́ odi Jerusalẹmu, kí á lè fi òpin sí ìtìjú tí ó dé bá wa.” Mo sọ fún wọn nípa bí Ọlọrun ṣe lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ mi ati nípa ọ̀rọ̀ tí ọba bá mi sọ. Wọ́n sì dáhùn pé, “Ẹ jẹ́ kí á múra kí á sì kọ́ ọ.” Wọ́n sì gbáradì láti ṣe iṣẹ́ rere náà. Ṣugbọn nígbà tí Sanbalati ará Horoni ati Tobaya iranṣẹ ọba, ará Amoni ati Geṣemu ará Arabia gbọ́, wọ́n ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n sì ń pẹ̀gàn wa pé, “Kí ni ẹ̀ ń ṣe yìí? Ṣé ẹ̀ ń dìtẹ̀ mọ́ ọba ni?” Mo fún wọn lésì pé, “Ọlọrun ọ̀run yóo mú wa ṣe àṣeyọrí, àwa iranṣẹ rẹ̀ yóo múra, a óo sì mọ odi náà, ṣugbọn ní tiyín, ẹ kò ní ìpín, tabi ẹ̀tọ́, tabi ìrántí ní Jerusalẹmu.” Eliaṣibu, Olórí alufaa, ati àwọn arakunrin rẹ̀ tí àwọn náà jẹ́ alufaa bíi rẹ̀ múra, wọ́n sì kọ́ Ẹnubodè Aguntan. Wọ́n yà á sí mímọ́ wọn sì ṣe àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, wọ́n yà á sí mímọ́ títí dé Ilé Ìṣọ́ Ọgọrun-un, ati títí dé Ilé Ìṣọ́ Hananeli. Ibẹ̀ ni àwọn ará Jẹriko ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Lẹ́yìn wọn ni Sakuri ọmọ Imiri bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, ó mọ abala tí ó tẹ̀lé e. Àwọn ọmọ Hasenaa ni wọ́n kọ́ Ẹnubodè Ẹja, wọ́n ṣe àwọn ẹnu ọ̀nà, wọ́n so àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, wọ́n sì ṣe ọ̀pá ìdábùú sí àwọn ìlẹ̀kùn náà. Lẹ́yìn wọn ni Meremoti, ọmọ Uraya, ọmọ Hakosi ṣe àtúnṣe abala ọ̀dọ̀ wọn. Lẹ́yìn wọn, Meṣulamu ọmọ Berekaya, ọmọ Meṣesabeli náà ṣe àtúnṣe abala ọ̀dọ̀ wọn. Lẹ́yìn wọn ni Sadoku, ọmọ Baana náà ṣe àtúnṣe abala tiwọn. Lẹ́yìn wọn, àwọn ará Tekoa ṣe àtúnṣe ọ̀dọ̀ tiwọn, ṣugbọn àwọn ọlọ́lá ààrin wọn kò lọ́wọ́ sí iṣẹ́ àtúnṣe náà. Joiada, ọmọ Pasea, ati Meṣulamu, ọmọ Besodeaya, ni wọ́n ṣe àtúnṣe Ẹnubodè Àtijọ́. Wọ́n ṣe ẹnu ọ̀nà, wọ́n ṣe àwọn ìlẹ̀kùn, wọ́n sì ṣe ọ̀pá ìdábùú sí wọn. Lẹ́yìn wọn ni àwọn Melataya, ará Gibeoni, Jadoni, ará Meronoti, ati àwọn ará Gibeoni ati àwọn ará Misipa tí wọ́n wà ní abẹ́ ìjọba Ìkọjá Odò ṣe àtúnṣe abala ọ̀dọ̀ tiwọn. Usieli ọmọ Hariaya alágbẹ̀dẹ wúrà ló ṣiṣẹ́ tẹ̀lé wọn. Lẹ́yìn wọn ni Hananaya, ọ̀kan ninu àwọn onítùràrí ṣe àtúnṣe ọ̀dọ̀ tirẹ̀, wọ́n sì ṣe é dé ibi Odi Gbígbòòrò. Lẹ́yìn wọn ni Refaaya ọmọ Huri, aláṣẹ ìdajì agbègbè Jerusalẹmu ṣe àtúnṣe abala tí ó kàn. Jedaaya ọmọ Harumafi ló ṣe àtúnṣe abala tí ó tẹ̀lé tiwọn, ó tún apá ibi tí ó kọjú sí ilé rẹ̀ ṣe. Lẹ́yìn wọn, Hatuṣi ọmọ Haṣabineya ṣe àtúnṣe tiwọn. Malikija, ọmọ Harimu, ati Haṣubu, ọmọ Pahati Moabu, ṣe àtúnṣe apá ibòmíràn ati Ilé Ìṣọ́ ìléru. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Ṣalumu ọmọ Haloheṣi, aláṣẹ apá keji agbègbè Jerusalẹmu ṣe àtúnṣe apá ọ̀dọ̀ tirẹ̀, àtòun ati àwọn ọmọbinrin rẹ̀. Hanuni ati àwọn tí ń gbé Sanoa tún Ẹnubodè Àfonífojì ṣe, wọ́n tún un kọ́, wọ́n sì ṣe àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀. Wọ́n ṣe àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, wọ́n sì tún odi rẹ̀ kọ́ ní ìwọ̀n ẹgbẹrun igbọnwọ (mita 450), sí Ẹnubodè Ààtàn. Malikija ọmọ Rekabu, aláṣẹ agbègbè Beti Hakikeremu, ṣe àtúnṣe Ẹnubodè Ààtàn, ó tún un kọ́, ó so àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ ó sì ṣe àwọn ìdábùú rẹ̀. Ṣalumu ọmọ Kolihose, aláṣẹ agbègbè Misipa tún Ẹnubodè Orísun ṣe, ó tún un kọ́, ó bò ó, ó sì ṣe àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ ati ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, ó sì tún mọ odi Adágún Ṣela ti ọgbà ọba títí kan àtẹ̀gùn tí ó wá láti ìlú Dafidi. Lẹ́yìn rẹ̀, Nehemaya ọmọ Asibuki, aláṣẹ ìdajì agbègbè Betisuri ṣe àtúnṣe dé itẹ́ Dafidi, títí dé ibi adágún àtọwọ́dá ati títí dé ilé àwọn akọni. Lẹ́yìn rẹ̀ ni àwọn ọmọ Lefi wọnyi ṣe àtúnṣe ọ̀dọ̀ tiwọn ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí: Rehumu ọmọ Bani ṣe àtúnṣe apá ọ̀dọ̀ tirẹ̀, lẹ́yìn rẹ̀ ni Haṣabaya, aláṣẹ ìdajì agbègbè Keila ṣe àtúnṣe agbègbè tirẹ̀. Àwọn arakunrin rẹ̀ ṣe àtúnṣe agbègbè tiwọn náà: Bafai ọmọ Henadadi, aláṣẹ ìdajì agbègbè Keila ṣe ti agbègbè rẹ̀. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Eseri ọmọ Jeṣua, aláṣẹ Misipa, náà ṣe àtúnṣe apá kan lára ibi ihamọra ní ibi igun odi. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Baruku, ọmọ Sabai, ṣe àtúnṣe láti apá ibi Igun odi títí dé ẹnu ọ̀nà ilé Eliaṣibu olórí alufaa. Lẹ́yìn rẹ̀, Meremoti, ọmọ Uraya, ọmọ Hakosi, ṣe àtúnṣe apá tiwọn láti ẹnu ọ̀nà ilé Eliaṣibu títí dé òpin ilé Eliaṣibu. Lẹ́yìn rẹ̀, àwọn alufaa, àwọn ará pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jọdani ṣe àtúnṣe ọ̀dọ̀ tiwọn. Lẹ́yìn wọn ni Bẹnjamini ati Haṣubu ṣe àtúnṣe apá ibi tí ó kọjú sí ilé wọn. Lẹ́yìn wọn, Asaraya ọmọ Maaseaya, ọmọ Ananaya ṣe àtúnṣe ní ẹ̀gbẹ́ ilé tirẹ̀. Lẹ́yìn rẹ̀, Binui, ọmọ Henadadi ṣe àtúnṣe apá ọ̀dọ̀ tirẹ̀: láti ilé Asaraya títí dé ibi Igun Odi. Palali, ọmọ Usai ṣe àtúnṣe ibi tí ó kọjú sí Igun Odi ati ilé ìṣọ́, láti òkè ilé ọba níbi ọgbà àwọn olùṣọ́. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Pedaaya, ọmọ Paroṣi, ati àwọn iranṣẹ tẹmpili tí wọn ń gbé Ofeli ṣe àtúnṣe tiwọn dé ibi tí ó kọjú sí Ẹnubodè Omi, ní ìhà ìlà oòrùn ati ilé ìṣọ́ tí ó yọgun jáde títí dé ibi odi Ofeli. Lẹ́yìn náà ni àwọn ará Tekoa ṣe àtúnṣe apá ibi tí ó kọjú sí ilé ìṣọ́ tí ó yọgun jáde títí dé Ofeli. Àwọn alufaa ni wọ́n tún Òkè Ẹnubodè Ẹṣin ṣe, olukuluku tún ibi tí ó kọjú sí ilé rẹ̀ ṣe. Lẹ́yìn wọn, Sadoku, ọmọ Imeri, ṣe àtúnṣe ibi tí ó kọjú sí ilé tirẹ̀. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Ṣemaaya, ọmọ Ṣekanaya, olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà ìhà ìlà oòrùn, ṣe àtúnṣe ọ̀dọ̀ tirẹ̀. Lẹ́yìn rẹ̀, Hananaya, ọmọ Ṣelemaya, ati Hanuni, ọmọkunrin kẹfa ti Salafu bí ṣe àtúnṣe apá ibòmíràn. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Meṣulamu, ọmọ Berekaya, ṣe àtúnṣe ibi tí ó kọjú sí yàrá rẹ̀. Lẹ́yìn rẹ̀ Malikija, ọ̀kan ninu àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà, ṣe àtúnṣe títí dé ilé àwọn iranṣẹ tẹmpili ati ilé àwọn oníṣòwò, níbi tí ó kọjú sí Ẹnu Ọ̀nà Mifikadi, ati títí dé yàrá òkè orígun odi. Àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà ati àwọn oníṣòwò sì ṣe àtúnṣe tí ó yẹ ní ààrin yàrá òkè orígun odi ati ti Ẹnu Ọ̀nà Aguntan. Nígbà tí Sanbalati gbọ́ pé a ti ń kọ́ odi náà, inú bíi gidigidi, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn Juu. Ó sọ lójú àwọn arakunrin rẹ̀ ati àwọn ọmọ ogun Samaria pé, “Kí ni àwọn Juu aláìlera wọnyi ń ṣé? Ṣé wọn yóo tún ìlú wọn kọ́ ni? Ṣé wọn yóo tún máa rúbọ ni? Ṣé ọjọ́ kan ṣoṣo ni wọ́n fẹ́ parí rẹ̀ ni? Ṣé wọn yóo lè yọ àwọn òkúta kúrò ninu àlàpà tí wọ́n wà, kí wọn sì fi òkúta tí ó ti jóná gbẹ́ òkúta ìkọ́lé?” Tobaya ará Amoni náà sì fara mọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ ni, bí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ bá gun orí ohun tí wọ́n mọ, tí wọn ń pè ní odi olókùúta, wíwó ni yóo wó o lulẹ̀!” Mo bá gbadura pé, “Gbọ́, Ọlọrun wa, nítorí pé wọ́n kẹ́gàn wa. Yí ẹ̀gàn wọn pada lé wọn lórí, kí o sì fi wọ́n lé alágbèédá lọ́wọ́ ní ilẹ̀ tí wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ. Má mójú fo àìdára wọn, má sì pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ kúrò ninu àkọsílẹ̀ tí ó wà níwájú rẹ, nítorí pé wọ́n ti mú ọ bínú níwájú àwọn tí wọn ń mọ odi.” Bẹ́ẹ̀ ni, à ń mọ odi náà, a mọ ọ́n já ara wọn yípo, ó sì ga dé ìdajì ibi tí ó yẹ kí ó ga dé, nítorí pé àwọn eniyan náà ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn. Ṣugbọn nígbà tí Sanbalati ati Tobaya ati àwọn ará Arabu, ati àwọn ará Amoni, ati àwọn ará Aṣidodu, gbọ́ pé a ti ń ṣe àtúnṣe àwọn odi Jerusalẹmu ati pé a ti ń dí àwọn ihò ibẹ̀, inú bí wọn gidigidi. Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí dìtẹ̀ láti wá gbógun ti Jerusalẹmu kí wọ́n lè dá rúkèrúdò sílẹ̀. Ṣugbọn a gbadura sí Ọlọrun wa, a sì yan àwọn olùṣọ́ láti máa ṣọ́ ibẹ̀ tọ̀sán-tòru. Àwọn ará Juda bẹ̀rẹ̀ sí kọrin pé, “Agbára àwa tí à ń ṣe iṣẹ́ ń dín kù, iṣẹ́ sì tún pọ̀ nílẹ̀; ǹjẹ́ a ó lè mọ odi náà mọ́ báyìí?” Àwọn ọ̀tá wa sì wí pé, “Wọn kò ní mọ ohun tí ń ṣẹlẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní rí wa títí tí a óo fi dé ọ̀dọ̀ wọn, tí a óo pa wọ́n, tí iṣẹ́ náà yóo sì dúró.” Ṣugbọn àwọn Juu tí wọn ń gbé ààrin wọn wá sí ọ̀dọ̀ wa ní ọpọlọpọ ìgbà, wọ́n sì sọ fún wa pé, “Láti gbogbo ilẹ̀ wọn ni wọn yóo ti dìde ogun sí wa.” Nítorí náà mo fi àwọn eniyan ṣọ́ gbogbo ibi tí odi ìlú bá ti gba ibi tí ilẹ̀ ti dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́, mo yan olukuluku ní ìdílé ìdílé, wọ́n ń ṣọ́ odi ní agbègbè wọn pẹlu idà, ọ̀kọ̀, ati ọrun wọn. Mo dìde, mo wò yíká, mo bá sọ fún àwọn ọlọ́lá ati àwọn ìjòyè, ati àwọn eniyan yòókù pé, “Ẹ má jẹ́ kí ẹ̀rù wọn bà yín. Ẹ ranti OLUWA tí ó tóbi tí ó sì bani lẹ́rù, kí ẹ sì jà fún àwọn arakunrin yín, ati àwọn ọmọkunrin yín, àwọn ọmọbinrin yín, ati àwọn iyawo yín, ati àwọn ilé yín.” Nígbà tí àwọn ọ̀tá wa ti gbọ́ pé a ti mọ àṣírí ète wọn, ati pé Ọlọrun ti da ìmọ̀ wọn rú, gbogbo wa pada sí ibi odi náà, olukuluku sì ń ṣe iṣẹ́ tirẹ̀. Láti ọjọ́ náà, ìdajì àwọn òṣìṣẹ́ mi ní ń bá iṣẹ́ odi mímọ lọ, ìdajì yòókù sì dira pẹlu ọ̀kọ̀, àṣíborí, ọrun ati aṣọ ogun. Àwọn ìjòyè sì wà lẹ́yìn gbogbo àwọn eniyan Juda, tí ń mọ odi lọ́wọ́. Àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́ ń fi ọwọ́ kan ṣiṣẹ́, wọ́n sì mú ohun ìjà ní ọwọ́ keji. Ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́ náà fi idà kọ́ èjìká bí ó ṣe ń mọ odi lọ. Ẹni tí ó ń fọn fèrè sì wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀dọ̀ mi. Mo sì sọ fún àwọn ọlọ́lá ati àwọn ìjòyè ati àwọn eniyan yòókù pé, “Iṣẹ́ náà pọ̀ gan-an, odi yìí sì gùn tóbẹ́ẹ̀ tí ó mú kí á jìnnà sí ara wa. Ibikíbi tí ẹ bá wà, tí ẹ bá ti gbọ́ fèrè, ẹ wá péjọ sọ́dọ̀ wa. Ọlọrun wa yóo jà fún wa.” Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe ń ṣe iṣẹ́ náà tí àwọn apá kan sì gbé idà lọ́wọ́ láti àárọ̀ di alẹ́. Mo tún sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Kí olukuluku ati iranṣẹ rẹ̀ sùn ní Jerusalẹmu, kí wọ́n lè máa ṣọ́ ìlú lálẹ́, kí wọ́n sì máa ṣiṣẹ́ ní ojú ọ̀sán.” Nítorí náà, àtèmi ati àwọn arakunrin mi, ati àwọn iranṣẹ mi, ati àwọn olùṣọ́ tí wọ́n tẹ̀lé mi, a kò bọ́ aṣọ lọ́rùn tọ̀sán-tòru, gbogbo wa ni a di ihamọra wa, tí a sì mú nǹkan ìjà lọ́wọ́. Ọpọlọpọ àwọn eniyan náà, atọkunrin atobinrin, bẹ̀rẹ̀ sí tako àwọn Juu, arakunrin wọn. Àwọn kan ń sọ pé, “Àwa, ati àwọn ọmọ wa, lọkunrin ati lobinrin, a pọ̀, ẹ jẹ́ kí á lọ wá ọkà, kí á lè máa rí nǹkan jẹ, kí á má baà kú.” Àwọn mìíràn ń sọ pé, “A ti fi ilẹ̀ oko wa yáwó, ati ọgbà àjàrà wa, ati ilé wa, kí á lè rówó ra ọkà nítorí ìyàn tí ó mú yìí.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn mìíràn ń sọ pé, “A ti yá owó láti lè san owó ìṣákọ́lẹ̀ lórí ilẹ̀ oko ati ọgbà àjàrà wa. Bẹ́ẹ̀ sì ni, bí àwọn arakunrin wa ti rí ni àwa náà rí, àwọn ọmọ wa kò yàtọ̀ sí tiwọn; sibẹsibẹ, à ń fi túlààsì mú àwọn ọmọ wa lọ sóko ẹrú, àwọn ọmọbinrin wa mìíràn sì ti di ẹrú pẹlu bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí nǹkan tí a lè ṣe láti dáwọ́ rẹ̀ dúró, nítorí pé ní ìkáwọ́ ẹlòmíràn ni oko wa ati ọgbà àjàrà wa wà.” Inú bí mi nígbà tí mo gbọ́ igbe wọn ati ohun tí wọn ń sọ. Mo rò ó lọ́kàn mi, mo sì dá àwọn ọlọ́lá ati àwọn ìjòyè lẹ́bi. Mo sọ fún wọn pé, “Ẹ̀ ń ni àwọn arakunrin yín lára.” Mo bá pe ìpàdé ńlá lé wọn lórí, mo sọ fún wọn pé, “Ní tiwa, a ti gbìyànjú níwọ̀n bí agbára wa ti mọ, a ti ra àwọn arakunrin wa tí wọ́n tà lẹ́rú fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn pada, ṣugbọn ẹ̀yin tún ń ta àwọn arakunrin yín, kí wọ́n baà lè tún tà wọ́n fún wa!” Wọ́n dákẹ́, wọn kò sì lè fọhùn. Mo wá sọ pé, “Ohun tí ẹ̀ ń ṣe kò dára. Ǹjẹ́ kò yẹ kí ẹ máa fi ìbẹ̀rù rìn ní ọ̀nà Ọlọrun, kí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá wa má baà máa kẹ́gàn wa? Pàápàá tí ó jẹ́ pé èmi ati àwọn arakunrin mi ati àwọn iranṣẹ mi ni à ń yá wọn ní owó ati oúnjẹ. Ẹ má gba èlé lọ́wọ́ wọn mọ́, ẹ sì jẹ́ kí á pa gbèsè wọn rẹ́. Ẹ dá ilẹ̀ oko wọn pada fún wọn lónìí, ati ọgbà àjàrà wọn, ati ọgbà igi olifi wọn, ati ilé wọn, ati ìdá kan ninu ọgọrun-un owó èlé tí ẹ gbà, ati ọkà, waini, ati òróró tí ẹ ti gbà lọ́wọ́ wọn.” Wọ́n sì dáhùn pé, “A óo dá gbogbo rẹ̀ pada, a kò sì ní gba nǹkankan lọ́wọ́ wọn mọ́. A óo ṣe bí o ti wí.” Mo bá pe àwọn alufaa, mo sì mú kí wọ́n jẹ́jẹ̀ẹ́ láti ṣe ohun tí wọ́n ṣèlérí pé àwọn yóo ṣe. Mo gbọn àpò ìgbànú mi, mo ní, “Báyìí ni Ọlọrun yóo gbọn gbogbo ẹni tí kò bá mú ẹ̀jẹ́ yìí ṣẹ kúrò ninu ilé rẹ̀ ati kúrò lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀. Ọlọrun yóo gbọn olúwarẹ̀ dànù lọ́wọ́ òfo.” Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní àpéjọpọ̀ náà sì ṣe “Amin”, wọ́n sì yin OLUWA. Àwọn eniyan náà sì mú ìlérí wọn ṣẹ. Siwaju sí i, láti ìgbà tí a ti yàn mí sí ipò gomina ní ilẹ̀ Juda, láti ogun ọdún tí Atasasesi ti jọba sí ọdún kejilelọgbọn, èmi ati arakunrin mi kò jẹ oúnjẹ tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún wa gẹ́gẹ́ bíi gomina. Àwọn gomina yòókù tí wọ́n jẹ ṣiwaju mi a máa ni àwọn eniyan lára, wọn a máa gba oúnjẹ mìíràn ati ọtí waini lọ́wọ́ wọn, yàtọ̀ sí ogoji ìwọ̀n Ṣekeli fadaka tí wọn ń gbà. Àwọn iranṣẹ wọn pàápàá a máa ni àwọn eniyan lára. Ṣugbọn, nítèmi, n kò ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé mo bẹ̀rù Ọlọrun. Gbogbo ara ni mo fi bá wọn ṣiṣẹ́ odi mímọ, sibẹ n kò gba ilẹ̀ kankan, gbogbo àwọn iranṣẹ mi náà sì péjú sibẹ láti ṣiṣẹ́. Siwaju sí i, aadọjọ (150) àwọn Juu ati àwọn ìjòyè ni wọ́n ń jẹun lọ́dọ̀ mi, yàtọ̀ sí àwọn tíí máa wá láti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wa ká. Mààlúù kan ati aguntan mẹfa tí ó dára ni wọ́n ń bá mi pa lojumọ, wọn a tún máa bá mi pa ọpọlọpọ adìẹ. Ní ọjọ́ kẹwaa kẹwaa ni wọ́n máa ń tọ́jú ọpọlọpọ waini sinu awọ fún mi. Sibẹsibẹ, n kò bèèrè owó oúnjẹ tí ó jẹ́ ẹ̀tọ́ gomina, nítorí pé ara tí ń ni àwọn eniyan pupọ jù. Áà! Ọlọrun mi, ranti mi sí rere nítorí gbogbo rere tí mo ti ṣe fún àwọn eniyan wọnyi. Nígbà tí wọ́n sọ fún Sanbalati ati Tobaya ati Geṣemu ará Arabia ati àwọn ọ̀tá wa yòókù pé a ti tún odi náà mọ, ati pé kò sí àlàfo kankan mọ́ (lóòótọ́ n kò tíì ṣe ìlẹ̀kùn sí àwọn ẹnubodè). Sanbalati ati Geṣemu ranṣẹ sí mi, wọ́n ní “Wá, jẹ́ kí á pàdé ní ọ̀kan ninu àwọn ìletò tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ono.” Ṣugbọn wọ́n ti pète láti ṣe mí ní ibi. Mo bá ranṣẹ pada sí wọn pé, mò ń ṣe iṣẹ́ pataki kan lọ́wọ́, kò ní jẹ́ kí n lè wá. Kò sì ní yẹ kí n dá iṣẹ́ náà dúró nítorí àtiwá rí wọn. Ìgbà mẹrin ni wọ́n ranṣẹ pè mí bẹ́ẹ̀, èsì kan náà sì ni mo fún wọn ní ìgbà mẹrẹẹrin. Ní ìgbà karun-un, Sanbalati rán iranṣẹ rẹ̀ kan sí mi, ó kọ lẹta ṣugbọn kò fi òǹtẹ̀ lu lẹta náà. Ohun tí ó kọ sinu lẹta náà ni pé: “A fi ẹ̀sùn kàn ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, Geṣemu náà sì jẹ́rìí sí i pé, ìwọ ati àwọn Juu ń pète láti dìtẹ̀, nítorí náà ni ẹ fi ń mọ odi yín. Ìwọ ni o sì ń gbèrò láti jọba lé wọn lórí, ati pé o tilẹ̀ ti yan àwọn wolii láti máa kéde nípa rẹ ní Jerusalẹmu pé, ‘Ọba kan wà ní Juda.’ Ó pẹ́ ni, ó yá ni, ọba yóo gbọ́ ìròyìn yìí. Nítorí náà, wá kí á jọ jíròrò nípa ọ̀rọ̀ náà.” Mo ranṣẹ pada sí i pé, “Ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rárá, o kàn sọ ohun tí o rò lọ́kàn ara rẹ ni.” Nítorí pé gbogbo wọn fẹ́ dẹ́rù bà wá, wọ́n lérò pé a óo jáwọ́ kúrò ninu iṣẹ́ náà, a kò sì ní lè parí rẹ̀ mọ́. Ṣugbọn adura mi nisinsinyii ni, “Kí Ọlọrun, túbọ̀ fún mi ní okun.” Ní ọjọ́ kan tí mo lọ sí ilé Ṣemaaya, ọmọ Delaaya, ọmọ Mehetabeli, tí wọ́n tì mọ́lé, ó ní “Jẹ́ kí á jọ pàdé ní ilé Ọlọrun ninu tẹmpili, nítorí wọ́n ń bọ̀ wá pa ọ́, alẹ́ ni wọ́n ó sì wá.” Ṣugbọn mo dá a lóhùn pé, “Ṣé irú mi ni ó yẹ kí ó sá lọ? Àbí irú mi ni ó yẹ kí ó sá lọ sinu tẹmpili kí ó lọ máa gbé ibẹ̀? N kò ní lọ.” Ó hàn sí mi pé kì í ṣe Ọlọrun ló rán an níṣẹ́ sí mi, ó kàn ríran èké sí mi ni, nítorí ti Tobaya ati Sanbalati tí wọ́n bẹ̀ ẹ́ lọ́wẹ̀. Wọ́n bẹ̀ ẹ́ lọ́wẹ̀ kí ó lè dẹ́rù bà mí, kí n lè ṣe bí ó ti wí, kí n dẹ́ṣẹ̀, kí wọ́n lè bà mí ní orúkọ jẹ́, kí wọ́n wá kẹ́gàn mi. Áà, Ọlọrun mi, ranti ohun tí Tobaya ati Sanbalati ati Noadaya, wolii obinrin, ṣe sí mi, ati àwọn wolii yòókù tí wọ́n fẹ́ máa dẹ́rù bà mí. A mọ odi náà parí ní ọjọ́ kẹẹdọgbọn oṣù Eluli. Ó gbà wá ní ọjọ́ mejilelaadọta. Nígbà tí àwọn ọ̀tá wa, ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wa ká gbọ́ nípa rẹ̀, ẹ̀rù bà wọ́n, ìtìjú sì mú wọn, nítorí wọ́n mọ̀ pé nípa ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun ni iṣẹ́ náà fi ṣeéṣe. Ati pé àwọn ọlọ́lá Juda ń kọ lẹta ranṣẹ sí Tobaya ní gbogbo àkókò yìí, Tobaya náà sì ń désì pada sí wọn. Nítorí pé ọpọlọpọ àwọn ará Juda ni wọ́n ti bá a dá majẹmu, nítorí àna Ṣekanaya ọmọ Ara ni: ọmọ rẹ̀ ọkunrin, Jehohanani, ló fẹ́ ọmọbinrin Meṣulamu, ọmọ Berekaya. Wọn a máa sọ gbogbo nǹkan dáradára tí ó ń ṣe lójú mi, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn a máa sọ ọ̀rọ̀ témi náà bá sọ fún un. Tobaya kò sì dẹ́kun ati máa kọ lẹta sí mi láti dẹ́rù bà mí. Lẹ́yìn tí a ti mọ odi náà tán, tí mo ti ṣe àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, tí mo sì ti yan àwọn olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà, ati àwọn akọrin ati àwọn ọmọ Lefi, mo yan arakunrin mi, Hanani, ati Hananaya, gomina ilé ìṣọ́, láti máa ṣe àkóso Jerusalẹmu, nítorí pé Hananaya jẹ́ olóòótọ́ ó sì bẹ̀rù Ọlọrun ju ọpọlọpọ àwọn yòókù lọ. Mo sọ fún wọn pé, wọn kò gbọdọ̀ ṣí ẹnu ibodè Jerusalẹmu títí tí oòrùn yóo fi máa ta ni lára, kí wọ́n sì máa ti ibodè náà, kí wọ́n fi ọ̀pá ìdábùú sí i lẹ́yìn kí àwọn olùṣọ́ tó kúrò lẹ́nu iṣẹ́. Kí wọ́n yan àwọn olùṣọ́ láàrin àwọn ọmọ Jerusalẹmu, kí olukuluku ní ibùdó tirẹ̀, kí wọ́n sì máa ṣọ́ ibi tí ó bá kọjú sí ilé wọn. Ìlú náà fẹ̀, ó sì tóbi, ṣugbọn àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀ kéré níye, kò sì tíì sí ilé níbẹ̀. Nígbà náà ni Ọlọrun fi sí mi lọ́kàn láti ranṣẹ pe àwọn ọlọ́lá jọ, ati àwọn olórí, ati àwọn eniyan yòókù, láti wá ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ wọn ní ìdílé ìdílé. Mo rí ìwé tí wọ́n kọ orúkọ àwọn ìdílé tí wọ́n kọ́kọ́ wá sí, mo sì rí ohun tí wọ́n kọ sinu wọn pé: Orúkọ àwọn eniyan agbègbè náà, tí wọ́n pada ninu àwọn tí Nebukadinesari ọba Babiloni kó lọ sí ìgbèkùn, tí wọ́n pada sí Jerusalẹmu ati Juda, tí olukuluku wọn sì pada sí ìlú rẹ̀ nìwọ̀nyí. Wọ́n jọ dé pẹlu Serubabeli, Jeṣua, Nehemaya, Asaraya, Raamaya, Nahamani, Modekai, Biliṣani, Misipereti, Bigifai, Nehumi, ati Baana. Iye àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ Israẹli nìyí: Àwọn ọmọ Paroṣi jẹ́ ẹgbaa, ó lé mejilelaadọsan-an (2,172). Àwọn ọmọ Ṣefataya jẹ́ ọrinlelọọdunrun ó dín mẹjọ (372). Àwọn ọmọ Ara jẹ́ ọtalelẹgbẹta ó dín mẹjọ (652). Àwọn ọmọ Pahati Moabu, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Jeṣua ati Joabu, jẹ́ ẹgbẹrinla ó lé mejidinlogun (2,818). Àwọn ọmọ Elamu jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹrinlelaadọta (1,254). Àwọn ọmọ Satu jẹ́ ojilelẹgbẹrin ó lé marun-un (845). Àwọn ọmọ Sakai jẹ́ ojidinlẹgbẹrin (760). Àwọn ọmọ Binui jẹ́ ojilelẹgbẹta ó lé mẹjọ (648). Àwọn ọmọ Bebai jẹ́ ẹgbẹta lé mejidinlọgbọn (628). Àwọn ọmọ Asigadi jẹ́ ẹgbaa ó lé ọọdunrun ati mejilelogun (2,322). Àwọn ọmọ Adonikamu jẹ́ ọtalelẹgbẹta ati meje (667). Àwọn ọmọ Bigifai jẹ́ ẹgbaa ó lé mẹtadinlaadọrin (2,067). Àwọn ọmọ Adini jẹ́ ọtalelẹgbẹta ó dín marun-un (655). Àwọn ọmọ Ateri tí wọn ń jẹ́ Hesekaya jẹ́ mejidinlọgọrun-un. Àwọn ọmọ Haṣumu jẹ́ ọọdunrun ó lé mejidinlọgbọn (328). Àwọn ọmọ Besai jẹ́ ọọdunrun ó lé mẹrinlelogun (324). Àwọn ọmọ Harifi jẹ́ aadọfa ó lé meji (112). Àwọn ọmọ Gibeoni jẹ́ marundinlọgọrun-un. Àwọn ará Bẹtilẹhẹmu ati Netofa jẹ́ ọgọsan-an ó lé mẹjọ (188). Àwọn ará Anatoti jẹ́ mejidinlaadoje (128). Àwọn ará Beti Asimafeti jẹ́ mejilelogoji. Àwọn ará Kiriati Jearimu ati Kefira ati Beeroti jẹ́ ọtadinlẹgbẹrin ó lé mẹta (743). Àwọn ará Rama ati Geba jẹ́ ẹgbẹta lé mọkanlelogun (621). Àwọn ará Mikimaṣi jẹ́ mejilelọgọfa (122). Àwọn ará Bẹtẹli ati Ai jẹ́ mẹtalelọgọfa (123). Àwọn ará Nebo keji jẹ́ mejilelaadọta. Àwọn ọmọ Elamu keji jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹrinlelaadọta (1,254). Àwọn ọmọ Harimu jẹ́ ọọdunrun ó lé ogún (320). Àwọn ọmọ Jẹriko jẹ́ ojilelọọdunrun ó lé marun-un (345). Àwọn ọmọ Lodi, Hadidi ati Ono jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé mọkanlelogun (721). Àwọn ọmọ Senaa jẹ́ ẹgbaaji ó dín aadọrin (3,930). Àwọn alufaa nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Jedaaya, tí wọ́n jẹ́ ti ìdílé Jeṣua, jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ó lé mẹtalelaadọrin (973). Àwọn ọmọ Imeri jẹ́ ẹgbẹrun ó lé mejilelaadọta (1,052). Àwọn ọmọ Paṣuri jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹtadinlaadọta (1,247). Àwọn ọmọ Harimu jẹ́ ẹgbẹrun ó lé mẹtadinlogun (1,017). Àwọn ọmọ Lefi nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Jeṣua, tí wọn ń jẹ́ Kadimieli, ní ìdílé Hodefa, jẹ́ mẹrinlelaadọrin. Àwọn akọrin nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Asafu jẹ́ mejidinlaadọjọ (148). Àwọn olùṣọ́ ẹnubodè nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Ṣalumu, àwọn ọmọ Ateri, àwọn ọmọ Talimoni, àwọn ọmọ Akubu, àwọn ọmọ Hatita, ati àwọn ọmọ Ṣobai. Gbogbo wọn jẹ́ mejidinlogoje (138). Àwọn iranṣẹ tẹmpili nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Siha, àwọn ọmọ Hasufa, ati àwọn ọmọ Tabaoti, àwọn ọmọ Kerosi, àwọn ọmọ Sia, ati àwọn ọmọ Padoni, àwọn ọmọ Lebana, àwọn ọmọ Hagaba, ati àwọn ọmọ Ṣalimai, àwọn ọmọ Hanani, àwọn ọmọ Gideli, ati àwọn ọmọ Gahari, àwọn ọmọ Reaaya, àwọn ọmọ Resini, ati àwọn ọmọ Nekoda, àwọn ọmọ Gasamu, àwọn ọmọ Usa, ati àwọn ọmọ Pasea, àwọn ọmọ Besai, àwọn ọmọ Meuni, ati àwọn ọmọ Nefuṣesimu, àwọn ọmọ Bakibuki, àwọn ọmọ Hakufa, ati àwọn ọmọ Harihuri, àwọn ọmọ Basiluti, àwọn ọmọ Mehida, ati àwọn ọmọ Hariṣa, àwọn ọmọ Barikosi, àwọn ọmọ Sisera, ati àwọn ọmọ Tema, àwọn ọmọ Nesaya, ati àwọn ọmọ Hatifa. Àwọn ọmọ àwọn iranṣẹ Solomoni nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Sotai, àwọn ọmọ Sofereti, ati àwọn ọmọ Perida, àwọn ọmọ Jaala, àwọn ọmọ Dakoni, ati àwọn ọmọ Gideli, àwọn ọmọ Ṣefataya, àwọn ọmọ Hatili, àwọn ọmọ Pokereti Hasebaimu, ati àwọn ọmọ Amoni. Gbogbo àwọn tí wọn ń ṣe iṣẹ́ iranṣẹ ninu tẹmpili ati àwọn ọmọ àwọn iranṣẹ Solomoni jẹ́ irinwo ó dín mẹjọ (392). Àwọn tí wọ́n wá láti Teli Mela, ati láti Teli Hariṣa, Kerubu, Adoni, ati Imeri, ṣugbọn tí wọn kò mọ ilé baba wọn tabi ibi tí wọ́n ti ṣẹ̀, tí kò sì sí ẹ̀rí tí ó dájú, bóyá ọmọ Israẹli ni wọ́n tabi wọn kì í ṣe ọmọ Israẹli nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Delaaya, àwọn ọmọ Tobaya, ati àwọn ọmọ Nekoda. Wọ́n jẹ́ ojilelẹgbẹta ó lé meji (642). Bákan náà ni àwọn ọmọ alufaa wọnyi: àwọn ọmọ Hobaaya, àwọn ọmọ Hakosi, ati àwọn ọmọ Basilai (tí wọ́n fẹ́ iyawo lára àwọn ọmọ Basilai ará Gileadi, ṣugbọn tí wọn tún ń jẹ́ orúkọ àwọn àna wọn.) Nígbà tí wọ́n wá orúkọ wọn ninu ìwé àkọsílẹ̀ tí wọn kò rí i, wọ́n yọ wọ́n kúrò lára àwọn alufaa, wọ́n sì kà wọ́n sí aláìmọ́. Gomina sọ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ fẹnu kan oúnjẹ mímọ́ jùlọ títí tí alufaa kan tí ó lè lo Urimu ati Tumimu yóo fi dé. Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní àpéjọpọ̀ náà jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ati ẹgbaa ó lé ojidinnirinwo (42,360), yàtọ̀ sí àwọn iranṣẹkunrin wọn ati àwọn iranṣẹbinrin wọn tí wọ́n jẹ́ ẹẹdẹgbaarin lé ọọdunrun ati mẹtadinlogoji (7,337), wọ́n sì ní àwọn akọrin tí wọ́n jẹ́ ojilerugba ó lé marun-un (245) lọkunrin ati lobinrin. Àwọn ẹṣin wọn jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé mẹrindinlogoji (736), àwọn ìbaaka wọn jẹ́ ojilerugba ó lé marun-un (245), àwọn ràkúnmí wọn jẹ́ ojilenirinwo ó dín marun-un (435), àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn sì jẹ́ ẹgbaata ó lé ọrindinlẹgbẹrin (6,720). Àwọn olórí ní ìdílé kọ̀ọ̀kan kópa ninu iṣẹ́ náà. Gomina fi ẹgbẹrun (1,000) ìwọ̀n diramu wúrà sí ilé ìṣúra ati aadọta àwo kòtò, ati ẹẹdẹgbẹta ó lé ọgbọ̀n (530) ẹ̀wù alufaa sí i. Àwọn kan ninu àwọn baálé baálé fi ọ̀kẹ́ kan (20,000) òṣùnwọ̀n diramu wúrà sí ilé ìṣúra ati ẹgbọkanla (2,200) òṣùnwọ̀n mina fadaka. Ohun tí àwọn eniyan yòókù fi sílẹ̀ ni ọ̀kẹ́ kan (20,000) ìwọ̀n diramu wúrà ati ẹgbaa (2,000) ìwọ̀n mina fadaka ati aṣọ àwọn alufaa mẹtadinlaadọrin. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn alufaa ṣe bẹ̀rẹ̀ sí gbé àwọn ìlú Juda, pẹlu àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn aṣọ́bodè, ati àwọn akọrin, ati díẹ̀ lára àwọn eniyan náà, pẹlu àwọn iranṣẹ tẹmpili, ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, kaluku ń gbé ìlú rẹ̀. Nígbà tí yóo fi di oṣù keje, àwọn ọmọ Israẹli ti wà ní àwọn ìlú wọn. Ní ọjọ́ kinni oṣù náà, gbogbo wọn pátá péjọ pọ̀ sí gbangba ìta níwájú Ẹnubodè Omi, wọ́n sì sọ fún Ẹsira, akọ̀wé, pé kí ó mú ìwé òfin Mose tí OLUWA fún àwọn ọmọ Israẹli wá. Ẹsira, alufaa, gbé ìwé òfin náà jáde siwaju àpéjọ náà, tọkunrin tobinrin, gbogbo àwọn tí wọ́n lè gbọ́ kíkà òfin náà kí ó sì yé wọn ni wọ́n péjọ, ní ọjọ́ kinni oṣù keje. Ẹsira ka ìwé òfin náà sí etígbọ̀ọ́ wọn. Ó kọjú sí ìta gbangba tí ó wà lẹ́bàá Ẹnubode Omi láti àárọ̀ kutukutu títí di ọ̀sán, níwájú tọkunrin tobinrin ati àwọn tí ọ̀rọ̀ òfin náà yé, gbogbo wọn ni wọ́n sì tẹ́tí sí ìwé òfin náà. Ẹsira, akọ̀wé, dúró lórí pèpéle tí wọ́n fi igi kàn fún un, fún ìlò ọjọ́ náà. Matitaya dúró ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, Ṣema, Anaaya, Uraya, Hilikaya ati Maaseaya dúró ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún rẹ̀, Pedaaya, Miṣaeli, Malikija, ati Haṣumu, Haṣibadana, Sakaraya ati Meṣulamu sì dúró ní ẹ̀gbẹ́ òsì rẹ̀. Ẹsira ṣí ìwé náà lójú gbogbo eniyan, nítorí pé ó ga ju gbogbo wọn lọ, bí ó ti ṣí ìwé náà gbogbo wọn dìde. Ẹsira yin OLUWA, Ọlọrun, tí ó tóbi, gbogbo àwọn eniyan náà gbé ọwọ́ wọn sókè, wọ́n dáhùn pé “Amin, Amin,” wọ́n tẹríba, wọ́n dojúbolẹ̀, wọ́n sì sin OLUWA. Àwọn ọmọ Lefi wọnyi: Jeṣua, Bani, Ṣerebaya, Jamini, Akubu, Ṣabetai, Hodaya, Maaseaya, Kelita, Asaraya, Josabadi, Hanani, ati Pelaaya ni wọ́n ń túmọ̀ àwọn òfin náà tí wọ́n sì ń ṣe àlàyé rẹ̀ fún àwọn eniyan wọn, gbogbo àwọn eniyan dúró ní ààyè wọn. Wọ́n ka òfin Ọlọrun ninu ìwé náà ketekete, wọ́n túmọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ṣe àlàyé rẹ̀ fún àwọn eniyan, ó sì yé wọn. Nehemaya tí ó jẹ́ gomina, ati Ẹsira, alufaa ati akọ̀wé, ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n kọ́ àwọn eniyan náà sọ fún gbogbo wọn pé, “Ọjọ́ mímọ́ ni ọjọ́ òní jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun yín. Ẹ má banújẹ́ tabi kí ẹ sọkún.” Nítorí pé gbogbo wọn ni wọ́n ń sọkún nígbà tí wọn ń gbọ́ ọ̀rọ̀ inú òfin náà. Nehemaya bá sọ fún wọn pé, “Ẹ máa lọ, ẹ jẹ ẹran ọlọ́ràá, ẹ mu waini dídùn, kí ẹ sì fi oúnjẹ ranṣẹ sí àwọn tí wọn kò bá ní, nítorí pé ọjọ́ mímọ́ ni ọjọ́ òní jẹ́ fún OLUWA wa, ẹ má sì banújẹ́, nítorí pé ayọ̀ OLUWA ni agbára yín.” Àwọn ọmọ Lefi rẹ àwọn eniyan náà lẹ́kún, wọ́n sọ fún wọn pé, “Ẹ dákẹ́, nítorí pé ọjọ́ mímọ́ ni ọjọ́ òní, ẹ má bọkàn jẹ́.” Gbogbo àwọn eniyan náà lọ, wọ́n jẹ, wọ́n mu, wọ́n sì fi oúnjẹ ati ohun mímu ranṣẹ sí àwọn eniyan wọn, wọ́n ń yọ ayọ̀ ńlá nítorí pé ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbọ́ yé wọn. Ní ọjọ́ keji, àwọn olórí ìdílé kọ̀ọ̀kan àwọn eniyan náà, pẹlu àwọn alufaa, ati àwọn ọmọ Lefi, péjọ sọ́dọ̀ Ẹsira, akọ̀wé, kí ó lè la ọ̀rọ̀ òfin náà yé wọn. Wọ́n rí i kà ninu òfin tí OLUWA fún Mose pé kí àwọn ọmọ Israẹli máa gbé inú àgọ́ ní àkókò àjọ̀dún oṣù keje, ati pé kí wọ́n kéde rẹ̀ ní gbogbo àwọn ìlú wọn ati ni Jerusalẹmu pé, “Ẹ lọ sí orí àwọn òkè, kí ẹ sì mú àwọn ẹ̀ka igi olifi wá, ati ti paini, ati ti mitili, ati imọ̀ ọ̀pẹ, ati ẹ̀ka àwọn igi mìíràn láti fi pàgọ́, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀.” Àwọn eniyan náà jáde, wọ́n sì lọ wá imọ̀ ọ̀pẹ ati ẹ̀ka igi wá, wọ́n sì pàgọ́ fún ara wọn, kaluku pàgọ́ sí orí ilé, ati sí àgbàlá ilé wọn ati sí àgbàlá ilé Ọlọrun pẹlu, wọ́n pàgọ́ sí ìta Ẹnubodè Omi ati sí ìta Ẹnubodè Efuraimu. Gbogbo àpéjọ àwọn tí wọ́n pada dé láti oko ẹrú pa àgọ́, wọ́n sì ń gbé inú àgọ́ wọn. Láti ìgbà ayé Joṣua ọmọ Nuni, títí di àkókò náà, àwọn ọmọ Israẹli kò pàgọ́ bẹ́ẹ̀ rí, gbogbo wọn sì yọ ayọ̀ ńlá. Lojoojumọ, láti ọjọ́ kinni títí di ọjọ́ tí àsè náà parí, ni wọ́n ń kà ninu ìwé òfin. Wọ́n ṣe àjọ̀dún àsè náà fún ọjọ́ meje, ní ọjọ́ kẹjọ, wọ́n pe àpéjọ tí ó lọ́wọ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí ó wà ninu àkọsílẹ̀. Ní ọjọ́ kẹrinlelogun oṣù kan náà, àwọn ọmọ Israẹli péjọ pọ̀, wọ́n gbààwẹ̀, wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀, wọ́n sì ku eruku sí orí wọn. Wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn àlejò, wọ́n dìde dúró, wọ́n sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn ati gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wọn. Wọ́n dúró ní ààyè wọn, wọ́n sì ka ìwé òfin OLUWA Ọlọrun wọn fún bíi wakati mẹta lọ́jọ́ náà. Lẹ́yìn náà, wọ́n jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún nǹkan bíi wakati mẹta, wọ́n sì sin OLUWA Ọlọrun wọn. Jeṣua, Bani, ati Kadimieli, Ṣebanaya, Bunni, Ṣerebaya, Bani, ati Kenani dúró lórí pèpéle àwọn ọmọ Lefi, wọ́n sì gbadura sókè sí OLUWA Ọlọrun wọn. Lẹ́yìn náà ni àwọn ọmọ Lefi wọnyi: Jeṣua, Kadimieli, Bani, Haṣabineya, Ṣerebaya, Hodaya, Ṣebanaya ati Petahaya, pè wọ́n pé, “Ẹ dìde dúró kí ẹ sì yin OLUWA Ọlọrun yín lae ati laelae. Ìyìn ni fún orúkọ rẹ̀ tí ó lógo, tí ó ga ju gbogbo ibukun ati ìyìn lọ.” Ẹsira ní: “Ìwọ nìkan ni OLUWA, ìwọ ni o dá ọ̀run, àní, ọ̀run tí ó ga jùlọ, ati gbogbo àwọn ìràwọ̀ tí ó wà lójú ọ̀run, ìwọ ni o dá ilé ayé ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀, ati àwọn òkun ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn. Ìwọ ni o mú kí gbogbo wọn wà láàyè, ìwọ sì ni àwọn ogun ọ̀run ń sìn. Ìwọ ni OLUWA, Ọlọrun, tí ó yan Abramu, tí o mú un jáde wá láti ìlú Uri tí ó wà ní ilẹ̀ Kalidea, tí o sì yí orúkọ rẹ̀ pada sí Abrahamu. O rí i pé ó ṣe olóòótọ́ sí ọ, O sì bá a dá majẹmu láti fún àwọn ìran rẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn ará Kenaani ati ti àwọn ará Hiti, ti àwọn ará Amori, ti àwọn ará Perisi, ti àwọn ará Jebusi ati ti àwọn ará Girigaṣi, o sì ti mú ìlérí náà ṣẹ nítorí pé olódodo ni ọ́. “O ti rí ìpọ́njú àwọn baba wa ní ilẹ̀ Ijipti o sì gbọ́ igbe wọn ní etí Òkun Pupa, o sì ṣe iṣẹ́ àmì ati ìyanu, o fi jẹ Farao níyà ati gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náà, nítorí pé wọ́n hùwà ìgbéraga sí àwọn baba wa, o gbé orúkọ ara rẹ ga gẹ́gẹ́ bí ó ti wà lónìí. O pín òkun sí meji níwájú wọn, kí wọ́n lè gba ààrin rẹ̀ kọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ, o sì sọ àwọn tí wọn ń lé wọn lọ sinu ibú bí ẹni sọ òkúta sinu omi. Ò ń fi ọ̀wọ̀n ìkùukùu darí wọn lọ́sàn-án, o sì ń fi ọ̀wọ̀n iná darí wọn lóru, ò ń tọ́ wọn sí ọ̀nà tí ó yẹ kí wọ́n rìn. O sọ̀kalẹ̀ sí orí òkè Sinai, o bá wọn sọ̀rọ̀ láti ọ̀run, o sì fún wọn ní ìlànà ati ìdájọ́ tí ó tọ̀nà ati àwọn òfin tòótọ́, O kọ́ wọn láti máa pa ọjọ́ ìsinmi rẹ mọ́, o sì tún pèsè ẹ̀kọ́, ìlànà, ati òfin fún wọn láti ọwọ́ Mose iranṣẹ rẹ. O fún wọn ní oúnjẹ láti ọ̀run wá nígbà tí ebi ń pa wọ́n, o sì ń fún wọn ní omi mu láti inú àpáta nígbà tí òùngbẹ ń gbẹ wọ́n. O ní kí wọ́n lọ gba ilẹ̀ tí o ti ṣèlérí láti fún wọn bí ohun ìní wọn. “Àwọn ati àwọn baba wa hùwà ìgbéraga, wọn ṣe orí kunkun, wọn kò sì pa òfin náà mọ́. Wọ́n kọ̀ wọn kò gbọ́ràn, wọn kò sì ranti àwọn ohun ìyanu tí o ṣe láàrin wọn, ṣugbọn wọ́n ṣoríkunkun, wọ́n sì yan olórí láti kó wọn pada sinu ìgbèkùn wọn ní Ijipti. Ṣugbọn Ọlọrun tíí dáríjì ni ni Ọ́, olóore ọ̀fẹ́ ati aláàánú sì ni ọ́, o kì í tètè bínú, o sì kún fún ìfẹ́ tí kìí yẹ̀, nítorí náà o kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀. Nígbà tí wọ́n tilẹ̀ yá ère ọmọ mààlúù, tí wọn ń sọ pé, ‘Ọlọrun wọn tí ó kó wọn kúrò ní ilẹ̀ Ijipti ni,’ tí wọ́n sì ń hu ìwà ìmúnibínú, nítorí àánú rẹ, o kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ sinu aṣálẹ̀. Ọ̀wọ̀n ìkùukùu tí ó ń tọ́ wọn sọ́nà kò fìgbà kan kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ́sàn-án, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀wọ̀n iná kò sì fi wọ́n sílẹ̀ lóru. Ó ń tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn lálẹ́, láti máa tọ́ wọn sí ọ̀nà tí wọn yóo máa rìn. O fún wọn ní ẹ̀mí rere rẹ láti máa kọ́ wọn, o kò dá mana rẹ dúró, o fi ń bọ́ wọn. O sì ń fún wọn ni omi mu nígbà tí òùngbẹ bá ń gbẹ wọ́n. Ogoji ọdún ni o fi bọ́ wọn ninu aṣálẹ̀, wọn kò sì ṣe àìní ohunkohun, aṣọ wọn kò gbó, ẹsẹ̀ wọn kò sì wú. O gba ọpọlọpọ ìjọba ati ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè fún wọn, o sì fi ibi gbogbo fún wọn. Wọ́n gba ilẹ̀ ìní Sihoni, ọba Heṣiboni, ati ti Ogu, ọba Baṣani. O jẹ́ kí ìrandíran wọn pọ̀ sí i bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, o sì kó wọn dé ilẹ̀ tí o ti ṣèlérí fún àwọn baba wọn pé wọn yóo lọ gbà. Àwọn ọmọ wọn lọ sí ilẹ̀ náà, wọ́n sì gbà á, o ṣẹgun àwọn ará Kenaani tí wọn ń gbé orí ilẹ̀ náà tẹ́lẹ̀, o sì fi wọ́n lé àwọn ọmọ Israẹli lọ́wọ́, àtàwọn, àtọba wọn, àtilẹ̀ wọn, kí àwọn ọmọ Israẹli lè ṣe wọ́n bí wọ́n bá ti fẹ́. Àwọn ọmọ Israẹli gba gbogbo àwọn ìlú olódi ati ilẹ̀ tí ó lẹ́tù lójú, wọ́n sì gba ilé tí ó kún fún ọpọlọpọ àwọn nǹkan dáradára, ati kànga, ọgbà àjàrà, igi olifi ati ọpọlọpọ igi eléso, nítorí náà wọ́n jẹ wọ́n yó, wọ́n sanra, wọ́n sì ń gbádùn ara wọn ninu oore ńlá rẹ. “Ṣugbọn, wọ́n ṣe àìgbọràn, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọ. Wọ́n pa àwọn òfin rẹ tì sí apákan, wọ́n pa àwọn wolii rẹ tí wọ́n ti ń kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n yipada sí ọ, wọ́n sì ń hùwà àbùkù sí ọ. Nítorí náà, o fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, àwọn ọ̀tá sì jẹ wọ́n níyà, nígbà tí ìyà ń jẹ wọ́n, wọ́n ké pè ọ́, o sì gbọ́ igbe wọn lọ́run, gẹ́gẹ́ bí àánú rẹ ńlá, o gbé àwọn kan dìde bíi olùgbàlà láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn. Ṣugbọn lẹ́yìn tí wọ́n ti ní ìsinmi tán, wọ́n tún ṣe nǹkan burúkú níwájú rẹ, o sì tún fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, àwọn ọ̀tá wọn ṣẹgun wọn. Sibẹsibẹ, nígbà tí wọ́n ronupiwada tí wọ́n sì gbadura sí ọ, o gbọ́ lọ́run, lọpọlọpọ ìgbà ni o sì gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àánú rẹ. Ò sì máa kìlọ̀ fún wọn kí wọ́n lè yipada sí òfin rẹ. Sibẹ wọn a máa hùwà ìgbéraga, wọn kìí sìí pa òfin rẹ mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀ wọn a máa ṣẹ̀ sí òfin rẹ, tí ó jẹ́ pé bí eniyan bá pamọ́, ẹni náà yóo yè. Ṣugbọn wọn ń dágunlá, wọ́n ń ṣe orí kunkun, wọn kò sì gbọ́ràn. Ọpọlọpọ ọdún ni o fi mú sùúrù pẹlu wọ́n, tí o sì ń kìlọ̀ fún wọn nípasẹ̀ Ẹ̀mí rẹ, láti ẹnu àwọn wolii rẹ, sibẹ wọn kò fetí sílẹ̀. Nítorí náà ni o ṣe jẹ́ kí àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà ṣẹgun wọn. Ṣugbọn nítorí àánú rẹ ńlá, o kò jẹ́ kí wọ́n parun patapata, bẹ́ẹ̀ ni o kò pa wọ́n tì, nítorí pé Ọlọrun olóore ọ̀fẹ́ ati aláàánú ni ọ́. “Nítorí náà, nisinsinyii Ọlọrun wa, Ọlọrun tí ó tóbi, tí ó sì lágbára, Ọlọrun tí ó bani lẹ́rù, Ọlọrun tí máa ń mú ìlérí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ṣẹ, má fi ojú kékeré wo gbogbo ìnira tí ó dé bá wa yìí, ati èyí tí ó dé bá àwọn ọba wa, ati àwọn olórí wa, àwọn alufaa wa, ati àwọn wolii wa, àwọn baba wa, ati gbogbo àwọn eniyan rẹ, láti ìgbà àwọn ọba Asiria títí di ìsinsìnyìí. Sibẹ, o jàre gbogbo ohun tí ó dé bá wa yìí, nítorí pé o ṣe olóòótọ́ sí wa, àwa ni a hùwà burúkú sí ọ. Àwọn ọba wa, ati àwọn ìjòyè wa, àwọn alufaa wa ati àwọn baba wa kọ̀, wọn kò pa òfin rẹ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tẹ̀lé ìlànà rẹ, wọn kò sì gbọ́ ìkìlọ̀ rẹ. Pẹlu, bí àwọn nǹkan rere tí o fún wọn ti pọ̀ tó, lórí ilẹ̀ tí ó tóbi tí ó sì dára tí o fún wọn. Wọn kò sìn ọ́ ní agbègbè ìjọba wọn, ati ninu oore nla rẹ tí o fun wọn, àní ninu ilẹ̀ ẹlẹ́tù lójú nla tí o bùn wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì yipada kúrò ninu iṣẹ́ burúkú wọn. Wò ó ẹrú ni wá lónìí lórí ilẹ̀ tí o fún àwọn baba wa pé kí wọ́n máa gbádùn àwọn èso inú rẹ̀ ati àwọn nǹkan dáradára ibẹ̀. Wò ó, a ti di ẹrú lórí ilẹ̀ náà. Àwọn ọrọ̀ inú rẹ̀ sì di ti àwọn ọba tí wọn ń mú wa sìn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, wọ́n ń lo agbára lórí wa ati lórí àwọn mààlúù wa bí ó ṣe wù wọ́n, a sì wà ninu ìpọ́njú ńlá.” Nítorí gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ wọnyi, a dá majẹmu, a sì kọ ọ́ sílẹ̀, àwọn ìjòyè wa, ati àwọn ọmọ Lefi ati àwọn alufaa fi ọwọ́ sí i, wọ́n sì fi èdìdì dì í. Àwọn tí wọ́n fi ọwọ́ sí ìwé náà tí wọ́n sì fi èdìdì dì í nìwọ̀nyí: Nehemaya, gomina, ọmọ Hakalaya, ati Sedekaya. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ alufaa wọnyi: Seraya, Asaraya, ati Jeremaya, Paṣuri, Amaraya, ati Malikija, Hatuṣi, Ṣebanaya, ati Maluki, Harimu, Meremoti, ati Ọbadaya, Daniẹli, Ginetoni, ati Baruku, Meṣulamu, Abija, ati Mijamini, Maasaya, Biligai, Ṣemaaya. Àwọn ni alufaa. Lẹ́yìn náà àwọn ọmọ Lefi wọnyi: Jeṣua ọmọ Asanaya, Binui ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Henadadi, ati Kadimieli, ati àwọn arakunrin wọn: Ṣebanaya ati Hodaya, Kelita, Pelaaya, ati Hanani, Mika, Rehobu, ati Haṣabaya, Sakuri, Ṣerebaya, ati Ṣebanaya, Hodaya, Bani, ati Beninu. Àwọn ìjòyè wọn tí wọ́n fọwọ́ sí ìwé náà ni: Paroṣi, Pahati Moabu, Elamu, Satu, ati Bani, Bunni, Asigadi, ati Bebai, Adonija, Bigifai, ati Adini, Ateri, Hesekaya ati Aṣuri, Hodaya, Haṣumu, ati Besai, Harifi, Anatoti, ati Nebai, Magipiaṣi, Meṣulamu, ati Hesiri, Meṣesabeli, Sadoku, ati Jadua, Pelataya, Hanani, ati Anaaya, Hoṣea, Hananaya, ati Haṣubu, Haloheṣi, Pileha, ati Ṣobeki, Rehumu, Haṣabina, ati Maaseaya, Ahija, Hanani, ati Anani, Maluki, Harimu, ati Baana. Àwọn eniyan yòókù, àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, àwọn aṣọ́nà, àwọn akọrin, àwọn iranṣẹ tẹmpili ati àwọn tí wọ́n ti ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí òfin Ọlọrun, àwọn iyawo wọn, àwọn ọmọ wọn ọkunrin, àwọn ọmọ wọn obinrin, gbogbo àwọn tí wọ́n gbọ́njú mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀, wọ́n parapọ̀ pẹlu àwọn arakunrin wọn ati àwọn ọlọ́lá wọn; wọ́n gégùn-ún, wọ́n sì búra pé àwọn ó máa pa òfin Ọlọrun mọ́, àwọn óo sì máa tẹ̀lé e, bí Mose iranṣẹ rẹ̀ ti fún wọn. Wọ́n óo máa ṣe gbogbo ohun tí OLUWA tíí ṣe Oluwa wọn paláṣẹ, wọn ó sì máa tẹ̀lé ìlànà ati òfin rẹ̀. A kò ní fi àwọn ọmọ wa obinrin fún àwọn ọmọ àwọn àlejò tí ń gbé ilẹ̀ wa, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní fẹ́ àwọn ọmọbinrin wọn fún àwọn ọmọ wa. Bí wọn bá sì kó ọjà tabi oúnjẹ wá tà ní ọjọ́ ìsinmi, a kò ní rà á lọ́wọ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi tabi ní ọjọ́ mímọ́ kankan. A óo sì yọ̀ǹda gbogbo èso ọdún keje keje, ati gbogbo gbèsè tí eniyan bá jẹ wá. A óo sì tún fẹnu kò sí ati máa dá ìdámẹ́ta ṣekeli wá fún iṣẹ́ ilé Ọlọrun wa lọdọọdun. A óo máa pèsè burẹdi ìfihàn ati ẹbọ ohun jíjẹ ìgbà gbogbo, ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, ẹbọ ọjọ́ ìsinmi, ati ti oṣù tuntun fún àwọn àsè tí wọ́n ti là sílẹ̀, ati fún gbogbo ohun mímọ́, fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ láti mú ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli kúrò, ati fún gbogbo iṣẹ́ ilé Ọlọrun wa. A ti dìbò láàrin àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi ati àwọn eniyan, bí wọn yóo ṣe máa ru igi wá sí ilé Ọlọrun wa, ní oníléjilé, ní ìdílé ìdílé, ní àwọn àkókò tí a yàn lọdọọdun, tí wọn yóo fi máa rúbọ lórí pẹpẹ OLUWA Ọlọrun wa, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin. A ti gbà á bí ojúṣe wa pé àkọ́so èso ilẹ̀ wa ati àkọ́so gbogbo èso igi wa lọdọọdun, ni a óo máa gbé wá sí ilé OLUWA. A óo máa mú àwọn àkọ́bí ọmọ wa, ati ti àwọn mààlúù wa lọ sí ilé Ọlọrun wa, fún àwọn alufaa tí wọn ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni àkọ́já ewébẹ̀ wa, ati àkọ́bí àwọn ẹran ọ̀sìn wa. Bẹ́ẹ̀ náà ni ìyẹ̀fun tí a kọ́kọ́ kù, ati ọrẹ wa, èso gbogbo igi, ọtí waini, ati òróró. A óo máa kó wọn tọ àwọn alufaa lọ sí gbọ̀ngàn ilé Ọlọrun wa. A óo sì máa mú ìdámẹ́wàá èso ilẹ̀ wa lọ fún àwọn ọmọ Lefi, nítorí pé àwọn ọmọ Lefi ni wọ́n máa ń gba ìdámẹ́wàá káàkiri gbogbo ilẹ̀ wa. Àwọn alufaa, ọmọ Aaroni yóo wà pẹlu àwọn ọmọ Lefi nígbà tí àwọn ọmọ Lefi bá ń gba ìdámẹ́wàá, àwọn ọmọ Lefi yóo yọ ìdámẹ́wàá gbogbo ìdámẹ́wàá tí wọ́n bá gbà lọ sí ilé Ọlọrun wa. Wọn óo kó o sinu gbọ̀ngàn ninu ilé ìpa-nǹkan-mọ́-sí. Àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn ọmọ Lefi yóo dá oúnjẹ, waini ati òróró jọ sinu àwọn gbọ̀ngàn, níbi tí àwọn ohun èlò tí a ti yà sí mímọ́ fún lílò ní ilé Ọlọrun wa, pẹlu àwọn alufaa tí wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ati àwọn olùṣọ́ tẹmpili, ati àwọn akọrin. A kò ní fi ọ̀rọ̀ ilé Ọlọrun wa falẹ̀. Àwọn olórí àwọn eniyan náà ń gbé Jerusalẹmu, àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù dìbò láti yan ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu eniyan mẹ́wàá mẹ́wàá láti lọ máa gbé Jerusalẹmu, ìlú mímọ́, àwọn mẹsan-an yòókù sì ń gbé àwọn ìlú yòókù. Àwọn eniyan náà súre fún àwọn tí wọ́n fa ara wọn kalẹ̀ láti lọ máa gbé Jerusalẹmu. Àwọn ìjòyè ní àwọn agbègbè wọn ń gbé Jerusalẹmu, ṣugbọn ní àwọn ìlú Juda, olukuluku àwọn ọmọ Israẹli ń gbé orí ilẹ̀ rẹ̀, ní ìlú wọn, títí kan àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, àwọn iranṣẹ tẹmpili, ati àwọn ìran iranṣẹ Solomoni. Àwọn ọmọ Juda kan, ati àwọn ọmọ Bẹnjamini kan ń gbé Jerusalẹmu. Àwọn ọmọ Juda náà ni: Ataaya, ọmọ Usaya, ọmọ Sakaraya, ọmọ Amaraya, ọmọ Ṣefataya, ọmọ Mahalaleli, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Pẹrẹsi. Bẹ́ẹ̀ náà ni Maaseaya, ọmọ Baruku, ọmọ Kolihose, ọmọ Hasaya, ọmọ Adaya, ọmọ Joiaribu, ọmọ Sakaraya, ọmọ ará Ṣilo. Gbogbo àwọn ọmọ Peresi tí wọn ń gbé Jerusalẹmu jẹ́ akọni, wọ́n jẹ́ ọtalenirinwo ó lé mẹjọ (468). Àwọn ọmọ Bẹnjamini ni: Salu ọmọ Meṣulamu, ọmọ Joẹdi, ọmọ Pedaaya, ọmọ Kolaya, ọmọ Maaseaya, ọmọ Itieli, ọmọ Jeṣaya. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Gabai ati Salai. Àpapọ̀ gbogbo àwọn ọmọ Bẹnjamini wá jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ó lé mejidinlọgbọn (928). Joẹli ọmọ Sikiri ni alabojuto wọn, Juda ọmọ Hasenua ni igbákejì rẹ̀ ní ìlú náà. Àwọn alufaa ni: Jedaaya ọmọ Joiaribu ati Jakini; Seraaya, ọmọ Hilikaya, ọmọ Meṣulamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraiotu, ọmọ Ahitubu, olórí ilé Ọlọrun, ati àwọn arakunrin wọn tí wọ́n jọ ṣe iṣẹ́ ilé náà, wọ́n jẹ́ ẹgbẹrin lé mejilelogun (822). Adaya ọmọ Jerohamu, ọmọ Pelalaya, ọmọ Amisi, ọmọ Sakaraya, ọmọ Paṣuri, ọmọ Malikija, ati àwọn arakunrin rẹ̀, àwọn baálé baálé lápapọ̀ jẹ́ ojilerugba ó lé meji (242). Amaṣisai, ọmọ Asareli, ọmọ Asai, ọmọ Meṣilemoti, ọmọ Imeri, ati àwọn arakunrin rẹ̀. Alágbára ati akọni eniyan ni wọ́n, wọ́n jẹ́ mejidinlaadoje (128). Sabidieli ọmọ Hagedolimu ni alabojuto wọn. Àwọn ọmọ Lefi ni: Ṣemaaya, ọmọ Haṣubu, ọmọ Asirikamu, ọmọ Haṣabaya, ọmọ Bunni. Ṣabetai ati Josabadi, láàrin àwọn olórí ọmọ Lefi, ni wọ́n ń bojútó àwọn iṣẹ́ òde ilé Ọlọrun. Matanaya ọmọ Mika, ọmọ Sabidi, ọmọ Asafu, ni olórí tí ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ìdúpẹ́ ninu adura, ati Bakibukaya tí ó jẹ́ igbákejì ninu àwọn arakunrin rẹ̀, Abuda, ọmọ Ṣamua, ọmọ Galali, ọmọ Jedutuni. Gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà ní ìlú mímọ́ náà jẹ́ ọrinlerugba ó lé mẹrin (284). Àwọn aṣọ́nà ni, Akubu, Talimoni ati àwọn arakunrin wọn, àwọn ni wọ́n ń ṣọ́ àwọn ẹnu ọ̀nà, wọ́n jẹ́ mejilelaadọsan-an (172). Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli yòókù, ati àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi wà ní àwọn ìlú Juda, kaluku sì ń gbé orí ilẹ̀ ìní rẹ̀. Ṣugbọn àwọn iranṣẹ tẹmpili ń gbé ilẹ̀ Ofeli, Siha ati Giṣipa sì ni olórí wọn. Usi ni alabojuto àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu. Usi yìí jẹ́ ọmọ Bani, ọmọ Haṣabaya, ọmọ Matanaya, ọmọ Mika, lára àwọn ọmọ Asafu tí wọ́n jẹ́ akọrin. Òun ni olùdarí ìsìn ninu ilé Ọlọrun. Ọba ti fi àṣẹ lélẹ̀ nípa iṣẹ́ àwọn akọrin, ètò sì wà fún ohun tí wọ́n gbọdọ̀ máa fún wọn lojoojumọ. Petahaya ọmọ Meṣesabeli, lára àwọn ọmọ Sera, ọmọ Juda, ni aṣojú ọba nípa gbogbo nǹkan tí ó bá jẹ mọ́ ti àwọn ọmọ Israẹli. Ọ̀rọ̀ lórí àwọn ìletò ati àwọn pápá oko wọn, àwọn ará Juda kan ń gbé Kiriati Ariba ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀, àwọn mìíràn sì ń gbé Diboni ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀, ati ní Jekabuseeli ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀, ati ní Jeṣua, ati ní Molada, ati ní Betipeleti, ní Hasariṣuali ati ní Beeriṣeba, ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀, ní Sikilagi ati ní Mekona ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀, ní Enrimoni, ní Sora, ati ní Jarimutu, ní Sanoa, ati Adulamu, ati àwọn ìletò àyíká wọn, ní Lakiṣi ati àwọn ìgbèríko rẹ̀, ati ní Aseka ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀. Wọ́n pàgọ́ láti Beeriṣeba títí dé àfonífojì Hinomu. Àwọn eniyan Bẹnjamini náà ń gbé Geba lọ sókè, títí dé Mikimaṣi, Aija, Bẹtẹli, ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀, ní Anatoti, Nobu, Ananaya ati Hasori, ní Rama ati Gitaimu, ní Hadidi, Seboimu, ati Nebalati, ní Lodi, ati Ono, àfonífojì àwọn oníṣọ̀nà. A sì pa àwọn ìpínlẹ̀ àwọn ọmọ Lefi kan ní Juda pọ̀ mọ́ ti àwọn ọmọ Bẹnjamini. Orúkọ àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n bá Serubabeli ọmọ Ṣealitieli ati Jeṣua dé nìwọ̀nyí: Seraaya, Jeremaya ati Ẹsira, Amaraya, Maluki, ati Hatuṣi, Ṣekanaya, Rehumu, ati Meremoti, Ido, Ginetoi, ati Abija, Mijamini, Maadaya, ati Biliga, Ṣemaaya, Joiaribu ati Jedaaya, Salu ati Amoku, Hilikaya, ati Jedaaya. Àwọn ni wọ́n jẹ́ olórí alufaa ati olórí àwọn arakunrin wọn ní ìgbà ayé Jeṣua. Àwọn ọmọ Lefi ni: Jeṣua, Binui ati Kadimieli; Ṣerebaya, Juda, ati Matanaya, tí òun pẹlu àwọn arakunrin rẹ̀ wà nídìí ètò àwọn orin ọpẹ́. Bakibukaya ati Uno arakunrin wọn a máa dúró kọjú sí wọn ní àkókò ìsìn. Joṣua ni baba Joiakimu, Joiakimu ni baba Eliaṣibu, Eliaṣibu ni baba Joiada, Joiada ni baba Jonatani, Jonatani sì ni baba Jadua. Nígbà tí Joiakimu jẹ́ olórí alufaa, àwọn alufaa wọnyi ní olórí baálé ní ìdílé tí a dárúkọ wọnyi: Meraya ni baálé ní ìdílé Seraaya, Hananaya ni baálé ní ìdílé Jeremaya, Meṣulamu ni baálé ní ìdílé Ẹsira, Jehohanani ni baálé ní ìdílé Amaraya, Jonatani ni baálé ní ìdílé Maluki, Josẹfu ni baálé ní ìdílé Ṣebanaya, Adina ni baálé ní ìdílé Harimu, Helikai ni baálé ní ìdílé Meraiotu, Sakaraya ni baálé ní ìdílé Ido, Meṣulamu ni baálé ní ìdílé Ginetoni, Sikiri ni baálé ní ìdílé Abija, Pilitai ni baálé ní ìdílé Miniamini ati Moadaya, Ṣamua ni baálé ní ìdílé Biliga, Jehonatani ni baálé ní ìdílé Ṣemaaya, Matenai ni baálé ní ìdílé Joiaribu, Usi ni baálé ní ìdílé Jedaaya, Kalai ni baálé ní ìdílé Salai, Eberi ni baálé ní ìdílé Amoku, Haṣabaya ni baálé ní ìdílé Hilikaya, Netaneli ni baálé ní ìdílé Jedaaya. Nígbà ayé Eliaṣibu ati Joiada, Johanani ati Jadua, àwọn ọmọ Lefi ati àwọn alufaa ṣe àkọsílẹ̀ àwọn baálé baálé ní ìdílé baba wọn títí di àkókò ìjọba Dariusi ọba Pasia. Àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn baálé baálé ninu àwọn ọmọ Lefi títí di ìgbà ayé Johanani ọmọ Eliaṣibu wà ninu ìwé Kronika. Àwọn tí wọ́n jẹ́ aṣiwaju ninu àwọn ọmọ Lefi nìwọ̀nyí: Haṣabaya, Ṣerebaya, ati Joṣua ọmọ Kadimieli pẹlu àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn dúró kọjú sí ara wọn, àwọn ìhà mejeeji yin Ọlọrun lógo wọ́n sì dúpẹ́ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Dafidi, eniyan Ọlọrun fi lélẹ̀. Matanaya, Bakibukaya ati Ọbadaya, ati Meṣulamu, Talimoni, ati Akubu ni wọ́n jẹ́ olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà bodè tí wọn ń ṣọ́ àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ní ẹnubodè. Gbogbo nǹkan wọnyi ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Joiakimu, ọmọ Jeṣua, ọmọ Josadaki, ati nígbà ayé Nehemaya, gomina, ati Ẹsira Alufaa ati akọ̀wé. Nígbà tí wọ́n fẹ́ ṣe ìyàsímímọ́ odi ìlú náà, wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ Lefi jọ láti gbogbo ibi tí wọ́n wà, wọ́n kó wọn wá sí Jerusalẹmu, láti wá fi tayọ̀tayọ̀ ṣe ìyàsímímọ́ náà pẹlu orin ọpẹ́ ati kimbali ati hapu. Àwọn ìdílé akọrin bá kó ara wọn jọ láti gbogbo agbègbè Jerusalẹmu ati láti àwọn ìletò tí ó wà ní àyíká Netofati, bákan náà ni láti Betigiligali ati láti ẹkùn Geba, ati Asimafeti, nítorí pé àwọn akọrin kọ́ ìletò fún ara wọn ní agbègbè Jerusalẹmu. Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi wẹ ara wọn mọ́, wọ́n sì ṣe ìwẹ̀mọ́ fún àwọn eniyan ati àwọn bodè ati odi ìlú náà. Mo bá kó àwọn ìjòyè Juda lọ sórí odi náà, mo sì yan ọ̀wọ́ meji pataki tí wọ́n ṣe ìdúpẹ́ tí wọ́n sì tò kọjá ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Àwọn kan tò lọ ní apá ọ̀tún odi náà lọ sí Ẹnubodè Ààtàn, lẹ́yìn náà, Hoṣaaya ati ìdajì àwọn ìjòyè Juda tẹ̀lé wọn, Ati Asaraya, Ẹsira ati Meṣulamu, Juda, Bẹnjamini ati Ṣemaaya, ati Jeremaya. Àwọn kan ninu àwọn ọmọ alufaa tẹ̀lé wọn pẹlu fèrè. Àwọn nìwọ̀nyí: Sakaraya, ọmọ Jonatani, ọmọ Ṣemaaya, ọmọ Matanaya, ọmọ Mikaaya, ọmọ Sakuri, ọmọ Asafu, ati àwọn arakunrin rẹ̀ wọnyi: Ṣemaaya, Asareli ati Milalai, Gilalai, Maai ati Netaneli, Juda, ati Hanani, pẹlu àwọn ohun èlò orin Dafidi eniyan Ọlọ́run. Ẹsira, akọ̀wé, ni ó ṣáájú, àwọn eniyan sì tẹ̀lé e. Ní Ẹnubodè Orísun, wọ́n gòkè lọ tààrà sí ibi àtẹ̀gùn ìlú Dafidi, ní igun odi ìlú, ní òkè ààfin Dafidi, títí lọ dé Ẹnubodè Omi ní apá ìlà oòrùn ìlú. Ọ̀wọ́ keji àwọn tí wọ́n wá ṣe ìdúpẹ́ gba apá òsì, èmi náà sì tẹ̀lé wọn, pẹlu ìdajì àwọn eniyan, a gba orí odi náà lọ, a kọjá Ilé-ìṣọ́ ìléru, lọ sí ibi Odi Gbígbòòrò. A rékọjá Ẹnubodè Efuraimu, a gba Ẹnubodè Àtijọ́, ati Ẹnubodè Ẹja ati Ilé-ìṣọ́ Hananeli ati Ilé-ìṣọ́ Ọgọrun-un, lọ sí Ẹnubodè Aguntan, wọ́n sì dúró ní Ẹnubodè àwọn Olùṣọ́ Tẹmpili. Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀wọ́ mejeeji àwọn tí wọ́n wá ṣe ìdúpẹ́ ṣe dúró ninu ilé Ọlọrun, ati èmi pẹlu ìdajì àwọn baálé baálé. Àwọn tí wọ́n tún wà pẹlu mi nìwọ̀nyí: àwọn alufaa: Eliakimu, Maaseaya ati Miniamini Mikaya, Elioenai, Sakaraya ati Hananaya, ń fun fèrè. Bẹ́ẹ̀ náà ni Maaseaya, Ṣemaaya, Eleasari ati Usi, Jehohanani, Malikija, Elamu, ati Eseri. Àwọn akọrin kọrin, Jesirahaya sì ni olórí wọn. Wọ́n ṣe ìrúbọ pataki ní ọjọ́ náà, wọ́n sì yọ̀, nítorí Ọlọrun jẹ́ kí wọ́n yọ ayọ̀ ńlá, àwọn obinrin wọn, ati àwọn ọmọ wọn náà yọ̀ pẹlu. Àwọn tí wọ́n wà lọ́nà jíjìn réré sì gbúròó igbe ayọ̀ ní Jerusalẹmu. Ní ọjọ́ náà, wọ́n yan àwọn kan láti mójútó àwọn ilé ìṣúra, ati ọrẹ tí àwọn eniyan dájọ, àwọn èso àkọ́so, ati ìdámẹ́wàá, àwọn tí wọ́n yàn ni wọ́n ń mójútó pípín ẹ̀tọ́ àwọn alufaa ati ti àwọn ọmọ Lefi, gẹ́gẹ́ bí ìlú wọn, bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ninu ìwé òfin. Inú àwọn ará ilẹ̀ Juda dùn pupọ sí àwọn alufaa ati sí àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń ṣe iṣẹ́ ìsìn. Wọ́n ṣe ìsìn Ọlọrun ati ìsìn ìyàsímímọ́ bí àwọn akọrin ati àwọn olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà tí ṣe, gẹ́gẹ́ bí òfin Dafidi ati ti ọmọ rẹ̀, Solomoni. Nítorí pé látijọ́, ní ìgbà ayé Dafidi ati Asafu, wọ́n ní olórí fún àwọn akọrin, wọ́n sì ní àwọn orin ìyìn ati orin ọpẹ́ sí Ọlọ́run. Nígbà ayé Serubabeli ati Nehemaya, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli a máa fún àwọn akọrin ati àwọn olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà ní ẹ̀tọ́ wọn ojoojumọ, wọn a máa ya ìpín àwọn ọmọ Lefi náà sọ́tọ̀, àwọn ọmọ Lefi náà a sì máa ya ìpín àwọn ọmọ Aaroni sọ́tọ̀. Ní ọjọ́ náà, wọ́n kà ninu ìwé Mose sí etígbọ̀ọ́ àwọn eniyan, ibẹ̀ sì ni a ti rí i kà pé àwọn ará Amoni ati àwọn ọmọ Moabu kò gbọdọ̀ wọ àwùjọ àwọn eniyan Ọlọrun, nítorí pé wọn kò gbé oúnjẹ ati omi lọ pàdé àwọn ọmọ Israẹli, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n bẹ Balaamu lọ́wẹ̀ láti máa gbé àwọn ọmọ Israẹli ṣépè, ṣugbọn Ọlọrun wa yí èpè náà pada sí ìre fún Israẹli. Nígbà tí àwọn eniyan gbọ́ òfin náà, wọ́n yọ gbogbo àwọn àjèjì jáde kúrò láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Kí ó tó di àkókò náà, Eliaṣibu alufaa, tí wọ́n yàn láti máa ṣe àkóso àwọn yàrá ilé Ọlọrun wa, tí ó sì ní àjọṣe pẹlu Tobaya, ó ṣètò yàrá ńlá kan fún Tobaya níbi tí wọ́n ń tọ́jú ọrẹ ẹbọ ohun jíjẹ sí, ati turari, àwọn ohun èlò ìrúbọ, pẹlu ìdámẹ́wàá ọkà, ati waini ati òróró tí wọ́n fún àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn akọrin, ati àwọn olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà, pẹlu àwọn ohun tí wọ́n dá jọ fún àwọn alufaa gẹ́gẹ́ bí òfin. N kò sí ní Jerusalẹmu ní gbogbo àkókò tí nǹkan wọnyi ṣẹlẹ̀, nítorí pé ní ọdún kejilelọgbọn ìjọba Atasasesi, ọba Babiloni, ni mo ti pada tọ ọba lọ. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, mo gba ààyè lọ́wọ́ ọba, mo sì wá sí Jerusalẹmu, ìgbà náà ni mo wá rí nǹkan burúkú tí Eliaṣibu ṣe nítorí Tobaya, tí ó yọ yàrá fún ninu àgbàlá ilé Ọlọrun. Inú bí mi gan-an, mo bá fọ́n gbogbo ẹrù Tobaya jáde kúrò ninu yàrá náà. Mo bá pàṣẹ pé kí wọ́n tún yàrá náà ṣe kí ó mọ́, ẹ̀yìn náà ni mo wá kó àwọn ohun èlò ilé Ọlọrun pada ati ọrẹ ẹbọ ohun sísun ati turari. Mo tún rí i wí pé wọn kò fún àwọn ọmọ Lefi ní ẹ̀tọ́ wọn, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Lefi ati àwọn akọrin, tí wọn ń ṣe iṣẹ́ náà fi sá lọ sí oko wọn. Nítorí náà, mo bá àwọn olórí wí, mo ní “Kí ló dé tí ilé Ọlọrun fi di àpatì?” Mo kó wọn jọ, mo sì dá wọn pada sí ààyè wọn. Gbogbo àwọn ọmọ Juda mú ìdámẹ́wàá ọkà, ati waini ati òróró wá sí ilé ìṣúra. Mo bá yan àwọn kan tí yóo máa mójútó ètò ìsúná owó ní àwọn ilé ìṣúra. Àwọn ni: Ṣelemaya, alufaa, Sadoku, akọ̀wé, ati Pedaaya, ọmọ Lefi. Ẹni tí ó jẹ́ igbákejì wọn ni Hanani ọmọ Sakuri, ọmọ Matanaya, nítorí pé wọ́n mọ̀ wọ́n sí olóòótọ́, iṣẹ́ wọn sì ni láti fún àwọn arakunrin wọn ní ẹ̀tọ́ wọn. Ọlọrun mi, ranti mi, nítorí nǹkan wọnyi, kí o má sì pa gbogbo nǹkan rere tí mo ti ṣe sí tẹmpili rẹ rẹ́ ati àwọn iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Ní àkókò náà mo rí àwọn ọmọ Juda tí wọn ń fún ọtí waini ní ọjọ́ ìsinmi, tí wọ́n sì ń kó ìtí ọkà jọ, tí wọn ń dì wọ́n ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, tí wọn sì ń gbé waini, ati èso girepu, ati igi ọ̀pọ̀tọ́ ati oríṣìíríṣìí ẹrù wúwo wá sí Jerusalẹmu ní ọjọ́ ìsinmi, mo bá kìlọ̀ fún wọn nípa ọjọ́ tí ó yẹ kí wọ́n máa ta oúnjẹ. Àwọn ọkunrin kan láti Tire pàápàá tí wọn ń gbé ààrin ìlú náà mú ẹja wá ati oríṣìíríṣìí àwọn nǹkan títà, wọ́n sì ń tà wọ́n fún àwọn eniyan Juda ati ni Jerusalẹmu ní ọjọ́ ìsinmi. Mo bá àwọn ọlọ́lá Juda wí, mo ní, “Irú nǹkan burúkú wo ni ẹ̀ ń ṣe yìí, tí ẹ̀ ń rú òfin ọjọ́ ìsinmi? Irú nǹkan burúkú yìí kọ́ ni àwọn baba yín pàápàá ṣe tí Ọlọrun fi mú kí ibi bá àwa ati ìlú yìí? Sibẹ, ẹ tún ń rú òfin ọjọ́ ìsinmi, ẹ̀ ń fa ìrúnú Ọlọrun sórí Israẹli.” Nígbà tí ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ṣú ní àwọn Ẹnubodè Jerusalẹmu kí ó tó di ọjọ́ ìsinmi, mo pàṣẹ pé kí wọ́n ti gbogbo ìlẹ̀kùn, ati pé wọn kò gbọdọ̀ ṣí i sílẹ̀ títí tí ọjọ́ ìsinmi yóo fi rékọjá. Mo yan díẹ̀ lára àwọn iranṣẹ mi sí àwọn ẹnubodè náà, kí wọ́n má baà kó ẹrù kankan wọlé ní ọjọ́ ìsinmi. Gbogbo àwọn oníṣòwò ati àwọn tí wọn ń ta oríṣìíríṣìí nǹkan sùn sí ẹ̀yìn odi Jerusalẹmu bíi ẹ̀ẹ̀kan tabi ẹẹmeji. Ṣugbọn mo kìlọ̀ fún wọn, mo sì sọ fún wọn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ odi? Bí ẹ bá tún ṣe bẹ́ẹ̀ n óo jẹ yín níyà.” Láti ìgbà náà ni wọn kò wá ní ọjọ́ ìsinmi mọ́. Mo kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Lefi pé kí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́, kí wọ́n wá láti ṣọ́ àwọn ẹnubodè, kí wọn lè pa ọjọ́ ìsinmi mọ́. Ranti eléyìí fún rere mi, Ọlọrun mi, kí o sì dá mi sí gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ńlá rẹ tí kì í yẹ̀. Nígbà náà, mo rí àwọn Juu tí wọn fẹ́ iyawo lára àwọn ará Aṣidodu, àwọn ará Amoni ati ti Moabu, ìdajì àwọn ọmọ wọn ni kò gbọ́ èdè Juda àfi èdè Aṣidodu. Èdè àwọn àjèjì nìkan ni wọ́n gbọ́. Mo bínú sí wọn mo sì gbé wọn ṣépè, mo na àwọn mìíràn, mo sì fa irun wọn tu. Mo sì mú wọn búra ní orúkọ Ọlọrun wí pé: “Ẹ kò gbọdọ̀ fi àwọn ọmọbinrin yín fún àwọn ọmọ wọn, tabi kí ẹ fẹ́ àwọn ọmọ wọn fún àwọn ọmọkunrin yín tabi kí ẹ̀yin pàápàá fẹ́mọ lọ́wọ́ wọn. Ṣebí Solomoni ọba pàápàá dẹ́ṣẹ̀ nítorí ó fẹ́ irú àwọn obinrin bẹ́ẹ̀. Kò sí ọba tí ó dàbí rẹ̀ láàrin àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, Ọlọrun sì fẹ́ràn rẹ̀, Ọlọrun sì fi jọba lórí gbogbo Israẹli, sibẹsibẹ, àwọn obinrin àjèjì ni wọ́n mú un dẹ́ṣẹ̀. Ṣé a óo wá tẹ̀lé ìṣìnà yín, kí á sì máa ṣe irú nǹkan burúkú yìí, kí á sì máa fẹ́ àwọn obinrin àjèjì tí ó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọrun wa?” Ọ̀kan ninu àwọn ọmọkunrin Jehoiada, ọmọ Eliaṣibu olórí alufaa, fẹ́ ọmọ Sanbalati ará Horoni kan, nítorí náà mo lé e kúrò lọ́dọ̀ mi. Ranti, Ọlọrun mi, nítorí pé wọ́n rú òfin àwọn alufaa, wọn kò sì mú ẹ̀jẹ́ àwọn alufaa ati ti àwọn ọmọ Lefi ṣẹ. Nítorí náà mo wẹ̀ wọ́n mọ́ ninu gbogbo nǹkan àjèjì, mo sì fi ìdí iṣẹ́ wọn múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alufaa ati ọmọ Lefi. Olukuluku sì ní iṣẹ́ tí ó ń ṣe, mo pèsè igi ìrúbọ, ní àkókò tí ó yẹ ati àwọn èso àkọ́so. Ranti mi sí rere, Ọlọrun mi. Ní àkókò tí Ahasu-erusi jọba ní ilẹ̀ Pasia, ìjọba rẹ̀ tàn dé agbègbè mẹtadinlaadoje (127), láti India títí dé Kuṣi ní ilẹ̀ Etiopia. Nígbà tí ó wà lórí oyè ní Susa tíí ṣe olú-ìlú ìjọba rẹ̀, ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó se àsè fún àwọn ìjòyè, ati àwọn olórí, àwọn òṣìṣẹ́, ati àwọn olórí ogun Pasia ati ti Media, àwọn eniyan pataki pataki tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ati àwọn gomina agbègbè rẹ̀. Fún odidi ọgọsan-an (180) ọjọ́ ni ọba fi ń fi ògo ìjọba rẹ̀ hàn, pẹlu ọrọ̀ ati dúkìá rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ọba se àsè ní àgbàlá ààfin fún ọjọ́ meje, fún gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní Susa, àtàwọn talaka, àtàwọn eniyan ńláńlá. Wọ́n ṣe ọgbà náà lọ́ṣọ̀ọ́ pẹlu aṣọ aláwọ̀ aró ati aṣọ funfun. Wọ́n fi òwú funfun ati òwú àlàárì ṣe okùn, wọ́n fi so wọ́n mọ́ òrùka fadaka, wọ́n gbé wọn kọ́ sára òpó òkúta mabu. Wúrà ati fadaka ni wọ́n fi ṣe àwọn àga tí ó wà ninu ọgbà. Òkúta mabu pupa ati aláwọ̀ aró ni wọ́n fi ṣe gbogbo ọ̀dẹ̀dẹ̀, tí gbogbo wọn ń dán gbinringbinrin. Wọ́n ń fi oríṣìíríṣìí ife wúrà mu ọtí, ọba sì pèsè ọtí lọpọlọpọ gẹ́gẹ́ bí ipò ọlá ńlá rẹ̀. Àṣẹ ọba ni wọ́n tẹ̀lé nípa ọ̀rọ̀ ọtí mímu. Wọn kò fi ipá mú ẹnikẹ́ni, nítorí pé ọba ti pàṣẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ ààfin pé ohun tí olukuluku bá fẹ́ ni kí wọn fi tẹ́ ẹ lọ́rùn. Ayaba Faṣiti pàápàá se àsè fún àwọn obinrin ní ààfin ọba Ahasu-erusi. Ní ọjọ́ keje, nígbà tí ọba mu ọtí waini tí inú rẹ̀ dùn, ó pàṣẹ fún meje ninu àwọn ìwẹ̀fà rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ iranṣẹ rẹ̀: Mehumani, Bisita ati Habona, Bigita ati Abagita, Setari ati Kakasi, pé kí wọ́n lọ mú Ayaba Faṣiti wá siwaju òun, pẹlu adé lórí rẹ̀, láti fi ẹwà rẹ̀ han gbogbo àwọn eniyan ati àwọn olórí, nítorí pé ó jẹ́ arẹwà obinrin. Ṣugbọn nígbà tí àwọn ìwẹ̀fà tí ọba rán jíṣẹ́ fún un, ó kọ̀, kò wá siwaju ọba. Nítorí náà, inú bí ọba gidigidi, inú rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí ru. Ọba bá fi ọ̀rọ̀ náà lọ àwọn ọlọ́gbọ́n tí wọ́n ní òye nípa àkókò, (nítorí bẹ́ẹ̀ ni ọba máa ń ṣe sí gbogbo àwọn tí wọ́n mọ òfin ati ìdájọ́. Àwọn tí wọ́n súnmọ́ ọn ni: Kaṣena, Ṣetari, ati Adimata, Taṣiṣi ati Meresi, Masena ati Memkani, àwọn ìjòyè meje ní Pasia ati Media. Àwọn ni wọ́n súnmọ́ ọn jù, tí ipò wọn sì ga jùlọ). Ọba bi wọ́n pé, “Gẹ́gẹ́ bí òfin, kí ni kí á ṣe sí Ayaba Faṣiti, nítorí ohun tí ọba pa láṣẹ, tí ó rán àwọn ìwẹ̀fà sí i pé kí ó ṣe kò ṣe é.” Memkani bá dáhùn níwájú ọba ati àwọn ìjòyè pé, “Kì í ṣe ọba nìkan ni Faṣiti kò kà sí, bíkòṣe gbogbo àwọn ìjòyè ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní agbègbè ìjọba Ahasu-erusi ọba. Nǹkan tí Faṣiti ṣe yìí yóo di mímọ̀ fún àwọn obinrin, àwọn náà yóo sì máa fi ojú tẹmbẹlu àwọn ọkọ wọn. Wọn yóo máa wí pé, ‘Ọba ṣá ti ranṣẹ sí ayaba pé kí ó wá siwaju òun rí, tí ó kọ̀, tí kò lọ.’ Láti òní lọ, àwọn obinrin, pàápàá àwọn obinrin Pasia ati ti Media, tí wọ́n ti gbọ́ ohun tí Ayaba ṣe yóo máa fi ṣe ọ̀rọ̀ sọ sí àwọn ìjòyè. Èyí yóo sì mú kí aifinipeni ati ibinu pọ̀ sí i. Nítorí náà bí ó bá wu ọba, kí ọba pàṣẹ, kí á sì kọ ọ́ sinu ìwé òfin Pasia ati ti Media, tí ẹnikẹ́ni kò lè yipada, pé Faṣiti kò gbọdọ̀ dé iwájú ọba mọ́, kí ọba sì fi ipò rẹ̀ fún ẹlòmíràn tí ó sàn jù ú lọ. Nígbà tí a bá kéde òfin yìí jákèjádò agbègbè rẹ, àwọn obinrin yóo máa bu ọlá fún àwọn ọkọ wọn; ọkọ wọn kì báà jẹ́ talaka tabi olówó.” Inú ọba ati àwọn ìjòyè dùn sí ìmọ̀ràn yìí, nítorí náà ọba ṣe bí Memkani ti sọ. Ó fi ìwé ranṣẹ sí gbogbo ilẹ̀ ìjọba rẹ̀, ati sí gbogbo agbègbè ati àwọn ẹ̀yà, ní èdè kaluku wọn, pé kí olukuluku ọkunrin máa jẹ́ olórí ninu ilé rẹ̀. Nígbà tí ó yá, tí ibinu ọba rọlẹ̀, ó ranti ohun tí Faṣiti ṣe, ati àwọn àṣẹ tí òun pa nípa rẹ̀. Àwọn iranṣẹ ọba tí wọ́n súnmọ́ ọn tímọ́tímọ́ bá sọ fún un pé, “Jẹ́ kí á wá àwọn wundia tí wọ́n lẹ́wà fún ọba, kí á yan àwọn eniyan ní gbogbo ìgbèríko ìjọba rẹ̀ láti ṣa àwọn wundia tí wọ́n lẹ́wà wá sí ibi tí àwọn ayaba ń gbé ní ààfin, ní Susa, tíí ṣe olú ìlú, kí wọ́n wà lábẹ́ ìtọ́jú Hegai, ìwẹ̀fà ọba, tíí ṣe olùtọ́jú àwọn ayaba, kí á sì fún wọn ní àwọn ohun ìpara, kí wundia tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn jù sì jẹ́ ayaba dípò Faṣiti.” Ìmọ̀ràn yìí dùn mọ́ ọba ninu, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ọkunrin kan, ará Juda láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini wà ní ààfin Susa, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Modekai, ọmọ Jairi, ọmọ Ṣimei, ọmọ Kiṣi. Ó wà lára àwọn tí Nebukadinesari ọba Babiloni kó lẹ́rú láti Jerusalẹmu lọ sí ilẹ̀ Babiloni pẹlu Jekonaya, ọba Juda. Modekai ń tọ́ ọmọbinrin kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hadasa tabi Ẹsita. Ọmọ yìí jẹ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ṣugbọn kò ní òbí mọ́. Ọmọ náà lẹ́wà gidigidi. Modekai mú un sọ́dọ̀ bí ọmọ ara rẹ̀, lẹ́yìn tí baba ati ìyá rẹ̀ ti kú. Nígbà tí ọba pàṣẹ, tí wọ́n kéde rẹ̀, tí wọ́n sì mú ọpọlọpọ wundia wá sí ààfin, ní Susa, ní abẹ́ ìtọ́jú Hegai, tí ń tọ́jú àwọn ayaba, Ẹsita wà pẹlu wọn ní ààfin ní abẹ́ ìtọ́jú rẹ̀. Ẹsita wú Hegai lórí, inú rẹ̀ dùn sí i pupọ. Ó fún un ní nǹkan ìpara ati oúnjẹ kíákíá. Ó tún fún un ní àwọn ọmọbinrin meje ninu àwọn iranṣẹbinrin tí wọ́n wà ní ààfin. Ó fún Ẹsita ati àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ ní ibi tí ó dára jùlọ ní ibi tí àwọn ayaba ń gbé. Ẹsita kò sọ inú ẹ̀yà tí òun ti wá, tabi ìdílé rẹ̀, fún ẹnikẹ́ni nítorí pé Modekai ti kìlọ̀ fún un pé kí ó má ṣe sọ nǹkankan nípa rẹ̀. Lojoojumọ ni Modekai máa ń rìn sókè sódò níwájú àgbàlá ibi tí àwọn ayaba ń gbé, láti bèèrè alaafia Ẹsita, ati bí ó ti ń ṣe sí. Kí wundia kankan tó lè lọ rí ọba, ó gbọdọ̀ kọ́ wà ninu ilé fún oṣù mejila, gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwọn obinrin wọn. Oṣù mẹfa ni wọ́n fi ń kun òróró ati òjíá, wọn á sì fi oṣù mẹfa kun òróró olóòórùn dídùn ati ìpara àwọn obinrin. Nígbà tí wundia kan bá ń lọ siwaju ọba, lẹ́yìn tí ó ba ti ṣe gbogbo nǹkan tí ó yẹ, ó lè gba ohunkohun tí ó bá fẹ́ mú lọ láti ilé àwọn ayaba. Yóo lọ sibẹ ní alẹ́, ní òwúrọ̀ yóo pada wá sí ilé keji tí àwọn ayaba ń lò, tí ó wà ní abẹ́ ìtọ́jú Ṣaaṣigasi, ìwẹ̀fà tí ó ń tọ́jú àwọn obinrin ọba. Kò tún ní pada lọ rí ọba mọ́, àfi bí inú ọba bá dùn sí i tí ó sì ranṣẹ pè é. Nígbà tí ó tó àkókò fún Ẹsita, ọmọ Abihaili ẹ̀gbọ́n Modekai, láti lọ rí ọba, Ẹsita kò bèèrè nǹkankan ju ohun tí Hegai, ìwẹ̀fà ọba tí ń tọ́jú àwọn ayaba, sọ fún un pé kí ó mú lọ. Ẹsita rí ojurere lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n rí i. Wọ́n mú Ẹsita lọ sọ́dọ̀ ọba Ahasu-erusi ní ààfin rẹ̀ ní oṣù Tebeti, tíí ṣe oṣù kẹwaa, ní ọdún keje ìjọba rẹ̀. Ọba fẹ́ràn rẹ̀ ju gbogbo àwọn obinrin yòókù lọ, ó sì rí ojurere ọba ju gbogbo àwọn wundia yòókù lọ. Ọba gbé adé lé e lórí, ó sì fi ṣe ayaba dípò Faṣiti. Ọba bá se àsè ńlá fún àwọn olóyè ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ nítorí Ẹsita. Ó fún gbogbo eniyan ní ìsinmi, ó sì fún wọn ní ọpọlọpọ ẹ̀bùn. Nígbà tí àwọn wundia péjọ ní ẹẹkeji, Modekai jókòó ní ẹnu ọ̀nà ààfin. Ṣugbọn Ẹsita kò sọ fún ẹnikẹ́ni nípa ẹ̀yà rẹ̀ ati àwọn eniyan rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Modekai ti pàṣẹ fún un, nítorí ó gbọ́ràn sí Modekai lẹ́nu, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe nígbà tí ó wà lábẹ́ ìtọ́jú rẹ̀. Ní àkókò náà, nígbà tí Modekai jókòó ní ẹnu ọ̀nà ààfin, meji ninu àwọn ìwẹ̀fà ọba, tí wọn ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà: Bigitana ati Tereṣi, ń bínú sí ọba, wọ́n sì ń dìtẹ̀ láti pa Ahasu-erusi ọba. Ṣugbọn Modekai gbọ́ nípa ọ̀tẹ̀ náà, ó sọ fún Ẹsita, ayaba, Ẹsita bá tètè lọ sọ fún ọba pé Modekai ni ó gbọ́ nípa ète náà tí ó sọ fún òun. Nígbà tí wọ́n wádìí ọ̀rọ̀ náà, tí wọ́n sì rí i pé òtítọ́ ni, wọ́n so àwọn ọlọ̀tẹ̀ mejeeji náà kọ́ sórí igi. Wọ́n sì kọ gbogbo rẹ̀ sílẹ̀ ninu ìwé ìtàn ìjọba níwájú ọba. Ahasu-erusi ọba gbé Hamani, ọmọ Hamedata, ará Agagi, ga ju gbogbo àwọn ìjòyè yòókù lọ. Gbogbo àwọn olóyè ní ẹnu ọ̀nà ààfin ọba a sì máa foríbalẹ̀ láti bu ọlá fún Hamani, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba, ṣugbọn Modekai kò jẹ́ foríbalẹ̀ kí ó bu ọlá fún Hamani. Àwọn olóyè kan ninu wọn bi Modekai léèrè pé, “Kí ló dé tí o fi ń tàpá sí àṣẹ ọba?” Ojoojumọ ni wọ́n ń kìlọ̀ fún un, ṣugbọn kò gbọ́. Nítorí náà, wọ́n lọ sọ fún Hamani, wọ́n fẹ́ mọ̀ bóyá ohun tí Modekai sọ ni yóo ṣẹ, nítorí ó sọ fún wọn pé Juu ni òun. Nígbà tí Hamani rí i pé Modekai kọ̀, kò foríbalẹ̀ fún òun, inú bí i pupọ. Nígbà tí ó mọ̀ pé Juu ni, ó kà á sí ohun kékeré láti pa Modekai nìkan, nítorí náà, ó pinnu láti pa gbogbo àwọn Juu tí wọ́n jẹ́ eniyan Modekai run, ní gbogbo ilẹ̀ ìjọba Ahasu-erusi. Ní ọdún kejila ìjọba Ahasu-erusi, Hamani pinnu láti yan ọjọ́ tí ó wọ̀, nítorí náà, ní oṣù kinni tíí ṣe oṣù Nisani, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́ gègé tí wọn ń pè ní Purimu, níwájú Hamani láti ọjọ́ dé ọjọ́ ati láti oṣù dé oṣù, títí dé oṣù kejila tíí ṣe oṣù Adari. Nígbà náà ni Hamani lọ bá Ahasu-erusi ọba, ó sọ fún un pé, “Àwọn eniyan kan wà tí wọ́n fọ́n káàkiri ààrin àwọn eniyan ati ní gbogbo agbègbè ìjọba rẹ; òfin wọn kò bá ti gbogbo eniyan mu, wọn kò sì pa àṣẹ ọba mọ́. Kò dára kí o gbà wọ́n láàyè ninu ìjọba rẹ. Bí ó bá dùn mọ́ Kabiyesi ninu, jẹ́ kí àṣẹ kan jáde lọ láti pa wọ́n run. N óo sì gbé ẹgbaarun (10,000) ìwọ̀n talẹnti fadaka fún àwọn tí a bá fi iṣẹ́ náà rán, kí wọ́n gbé e sí ilé ìṣúra ọba.” Ọba bọ́ òrùka àṣẹ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀, ó fún Hamani, ọmọ Hamedata, ará Agagi, ọ̀tá àwọn Juu. Ọba sọ fún un pé, “Má wulẹ̀ san owó kankan, àwọn eniyan náà wà ní ìkáwọ́ rẹ, lọ ṣe wọ́n bí o bá ti fẹ́.” Ní ọjọ́ kẹtala, oṣù kinni, Hamani pe àwọn akọ̀wé ọba jọ, wọ́n sì kọ gbogbo àṣẹ tí Hamani pa sinu ìwé. Wọ́n fi ìwé náà ranṣẹ sí àwọn gomina agbègbè ati àwọn olórí àwọn eniyan ati sí àwọn agbègbè kọ̀ọ̀kan ati ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn. Wọ́n kọ ìwé náà ní orúkọ ọba, wọ́n sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì rẹ̀. Wọ́n fi àwọn ìwé náà rán àwọn òjíṣẹ́ sí gbogbo agbègbè ọba pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn Juu run, ati kékeré ati àgbà, ati obinrin ati ọmọde ní ọjọ́ kan náà, tíí ṣe ọjọ́ kẹtala oṣù kejila oṣù Adari, kí wọ́n sì kó gbogbo ohun ìní wọn. Wọ́n níláti sọ ohun tí ó wà ninu ìwé náà di òfin ní gbogbo ìgbèríko, kí wọ́n sì sọ fún gbogbo eniyan, kí wọ́n lè múra sílẹ̀ de ọjọ́ náà. Wọ́n pa àṣẹ náà ní Susa tíí ṣe olú-ìlú, àwọn òjíṣẹ́ sì yára mú un lọ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba. Lẹ́yìn náà, Hamani ati ọba jókòó láti mu ọtí, ṣugbọn gbogbo ìlú Susa wà ninu ìdààmú. Nígbà tí Modekai gbọ́ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó fa aṣọ rẹ̀ ya. Ó fi àkísà ati eérú bo ara rẹ̀. Ó kígbe lọ sí ààrin ìlú, ó ń pohùnréré ẹkún. Ó lọ sí ẹnu ọ̀nà ààfin, ṣugbọn kò wọlé nítorí ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wọ àkísà wọ inú ààfin. Ní gbogbo agbègbè ati káàkiri ibi tí òfin ati àṣẹ ọba dé, ni àwọn Juu tí ń ṣọ̀fọ̀ tí wọn ń gbààwẹ̀ tẹkúntẹkún. Ọpọlọpọ wọn da aṣọ ọ̀fọ̀ bora, wọ́n sì da eérú sára. Nígbà tí àwọn iranṣẹbinrin Ẹsita ati àwọn ìwẹ̀fà rẹ̀ sọ fún un nípa Modekai, ọkàn rẹ̀ dàrú. Ó kó aṣọ ranṣẹ sí i, kí ó lè pààrọ̀ àkísà rẹ̀, ṣugbọn Modekai kọ̀ wọ́n. Ẹsita bá pe Hataki, ọ̀kan ninu àwọn ìwẹ̀fà ọba, tí ọba ti yàn láti máa ṣe iranṣẹ fún un. Ó pàṣẹ fún un pé kí ó lọ bá Modekai kí ó bèèrè ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ati ohun tí ó fà á. Hataki lọ bá Modekai ní ìta gbangba, níwájú ẹnu ọ̀nà ààfin ọba. Modekai sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún un, títí kan iye owó tí Hamani ti pinnu láti gbé kalẹ̀ sí ilé ìṣúra ọba kí wọ́n fi pa àwọn Juu run. Modekai fún Hataki ní ìwé òfin tí wọ́n ṣe ní Susa láti pa gbogbo àwọn Juu run patapata, pé kí ó fi ìwé náà han Ẹsita, kí ó sì là á yé e, kí ó lè lọ siwaju ọba láti bẹ̀ ẹ́ pé kí ó ṣàánú àwọn eniyan rẹ̀. Hataki pada lọ ròyìn ohun tí Modekai sọ fún Ẹsita. Ẹsita tún rán an pada sí Modekai pé, “Gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ati gbogbo eniyan ni wọ́n mọ̀ pé bí ẹnikẹ́ni bá lọ sọ́dọ̀ ọba ninu yàrá inú lọ́hùn-ún, láìṣe pé ọba pè é, òfin kan tí ọba ní fún irú eniyan bẹ́ẹ̀ ni pé kí á pa á, àfi bí ọba bá na ọ̀pá wúrà tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ sí ẹni náà ni wọn kò fi ní pa á. Ṣugbọn ó ti tó ọgbọ̀n ọjọ́ sẹ́yìn tí ọba ti pè mí.” Nígbà tí Modekai gbọ́ ìdáhùn yìí láti ọ̀dọ̀ Ẹsita, ó tún ranṣẹ sí Ẹsita pada, ó ní, “Má rò pé ìwọ nìkan óo là láàrin àwọn Juu, nítorí pé o wà ní ààfin ọba. Bí o bá dákẹ́ ní irú àkókò yìí, ìrànlọ́wọ́, ati ìgbàlà yóo ti ibòmíràn wá fún àwọn Juu, ṣugbọn a óo pa ìwọ ati àwọn ará ilé baba rẹ run. Ta ni ó sì lè sọ, bóyá nítorí irú àkókò yìí ni o fi di ayaba?” Ẹsita bá ranṣẹ sí Modekai, ó ní, “Lọ kó gbogbo àwọn Juu tí wọ́n wà ní Susa jọ, kí ẹ gba ààwẹ̀ fún mi fún ọjọ́ mẹta, láìjẹ, láìmu, láàárọ̀ ati lálẹ́. Èmi ati àwọn iranṣẹ mi náà yóo máa gbààwẹ̀ níhìn-ín. Lẹ́yìn náà, n óo lọ rí ọba, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lòdì sí òfin, bí n óo bá kú, kí n kú.” Modekai bá lọ, ó ṣe bí Ẹsita ti pàṣẹ fún un. Ní ọjọ́ kẹta, Ẹsita wọ aṣọ oyè rẹ̀, ó dúró ní àgbàlá ààfin ọba, ó kọjú sí gbọ̀ngàn ọba. Ọba jókòó lórí ìtẹ́ ninu gbọ̀ngàn rẹ̀, ó kọjú sí ẹnu ọ̀nà. Nígbà tí ó rí Ẹsita tí ó dúró ní ìta, inú rẹ̀ dùn sí i, ọba na ọ̀pá oyè tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ sí i, Ẹsita sì na ọwọ́, ó fi kan ṣóńṣó ọ̀pá náà. Ọba bi ayaba Ẹsita pé, “Ẹsita, kí ló dé? Kí ni ẹ̀dùn ọkàn rẹ? A óo fún ọ, títí dé ìdajì ìjọba mi.” Ẹsita bá dáhùn pé, “Bí inú kabiyesi bá dùn sí mi, mo fẹ́ kí kabiyesi ati Hamani wá sí ibi àsè tí n óo sè fun yín ní alẹ́ òní.” Ọba pàṣẹ pé, “Ẹ lọ pe Hamani wá kíákíá, kí á lè lọ ṣe ohun tí Ẹsita bèèrè.” Bẹ́ẹ̀ ni ọba ati Hamani ṣe lọ sí ibi àsè tí Ẹsita ti sè sílẹ̀. Bí wọn tí ń mu ọtí, ọba tún bi Ẹsita léèrè pé, “Kí ni ìbéèrè rẹ Ẹsita, a óo ṣe é fún ọ, kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ, gbogbo rẹ̀ ni a óo jẹ́ kí ó tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́ títí dé ìdajì ìjọba mi.” Ẹsita bá dáhùn pé, “Ìbéèrè ati ẹ̀bẹ̀ mi ni pé, bí inú kabiyesi bá dùn sí mi láti ṣe ohun tí mò ń fẹ́, ati láti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi, kí kabiyesi ati Hamani wá síbi àsè tí n óo sè fún wọn ní ọ̀la. Nígbà náà ni n óo sọ ohun tí ó wà ní ọkàn mi.” Hamani jáde pẹlu ayọ̀ ńlá, ati ìdùnnú. Ṣugbọn nígbà tí ó rí Modekai ní ẹnu ọ̀nà ààfin, tí kò tilẹ̀ mira rárá tabi kí ó wárìrì, inú bí i sí Modekai. Ṣugbọn Hamani pa á mọ́ra, ó lọ sí ilé rẹ̀. Ó pe gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ati iyawo rẹ̀ tí ń jẹ́ Sereṣi, ó bẹ̀rẹ̀ sí fọ́nnu fún wọn bí ọrọ̀ rẹ̀ ti pọ̀ tó, iye àwọn ọmọ rẹ̀, bí ọba ṣe gbé e ga ju gbogbo àwọn ìjòyè ati àwọn olórí yòókù lọ. Hamani tún fi kún un pé “Ayaba Ẹsita kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni bá ọba wá sí ibi àsè rẹ̀, àfi èmi nìkan. Ó sì ti tún pe èmi ati ọba sí àsè mìíràn ní ọ̀la. Ṣugbọn gbogbo nǹkan wọnyi kò lè tẹ́ mi lọ́rùn, bí mo bá ń rí Modekai, Juu, tí ó ń jókòó ní ẹnu ọ̀nà ààfin ọba.” Sereṣi iyawo rẹ̀ ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ fún un, pé, “Lọ ri igi tí wọn ń gbé eniyan kọ́, kí ó ga ní ìwọ̀n aadọta igbọnwọ. Bí ilẹ̀ bá ti mọ́, sọ fún ọba pé kí ó so Modekai kọ́ sí orí igi náà. Nígbà náà inú rẹ yóo dùn láti lọ sí ibi àsè náà.” Inú Hamani dùn sí ìmọ̀ràn yìí, ó lọ ri igi náà mọ́lẹ̀. Ní òru ọjọ́ náà, ọba kò lè sùn. Ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n gbé ìwé àkọsílẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìjọba rẹ̀ wá, kí wọ́n sì kà á sí etígbọ̀ọ́ òun. Wọ́n kà á ninu àkọsílẹ̀ pé Modekai tú àṣírí Bigitana ati Tereṣi, àwọn ìwẹ̀fà meji tí wọn ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ilé ọba, tí wọ́n dìtẹ̀ láti pa Ahasu-erusi ọba. Ọba bèèrè pé irú ọlá wo ni a dá Modekai fún ohun tí ó ṣe yìí? Wọ́n dá a lóhùn pé ẹnikẹ́ni kò ṣe nǹkankan fún un. Ọba bèèrè pé, “Ta ló wà ninu àgbàlá?” Àkókò náà ni Hamani wọ inú àgbàlá ààfin ọba, láti bá ọba sọ̀rọ̀ láti so Modekai rọ̀ sórí igi tí ó rì mọ́lẹ̀. Àwọn iranṣẹ ọba dá a lóhùn pé, “Hamani wà níbẹ̀ tí ó ń duro ní àgbàlá.” Ọba sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí ó wọlé.” Bí Hamani tí ń wọlé ni ọba bi í pé, “Kí ló yẹ kí á ṣe fún ẹni tí inú ọba dùn sí?” Hamani rò ó ninu ara rẹ̀ pé, ta ni ọba ìbá tún dá lọ́lá bíkòṣe òun. Nítorí náà, ó dá ọba lóhùn pé, “Báyìí ni ó ṣe yẹ kí á dá ẹni tí inú ọba dùn sí lọ́lá: kí wọ́n mú aṣọ ìgúnwà ọba, tí ọba ti wọ̀ rí, ati ẹṣin tí ó ti gùn rí, kí wọ́n sì fi adé ọba dé ẹni náà lórí, kí wọ́n kó wọn fún ọ̀kan ninu àwọn ìjòyè ọba tí ó ga jùlọ, kí ó fi ṣe ẹni náà lọ́ṣọ̀ọ́, kí ó gbé e gun ẹṣin, kí ó sì fà á káàkiri gbogbo ìlú, kí ó máa kéde pé, ‘Ẹ wo ohun tí ọba ṣe fún ẹni tí inú rẹ̀ dùn sí láti dá a lọ́lá.’ ” Ọba bá sọ fún Hamani pé, “Yára lọ mú aṣọ ìgúnwà, ati ẹṣin náà, kí o sì ṣe bí o ti wí sí Modekai, Juu, tí ó máa ń jókòó sí ẹnu ọ̀nà ààfin.” Hamani lọ mú ẹ̀wù ati ẹṣin náà, ó ṣe Modekai lọ́ṣọ̀ọ́, ó gbé e gun ẹṣin, ó sì ń ké níwájú rẹ̀ bí ó ti ń fà á káàkiri gbogbo ìlú pé, “Ẹ wo ohun tí ọba ṣe fún ẹni tí inú rẹ̀ dùn sí láti dá lọ́lá.” Lẹ́yìn náà, Modekai pada sí ẹnu ọ̀nà ààfin, ṣugbọn Hamani sáré pada lọ sí ilé rẹ̀ pẹlu ìbànújẹ́, ó sì bo orí rẹ̀. Ó sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i fún Sereṣi, iyawo rẹ̀, ati gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ ati iyawo rẹ̀ sọ fún un pé, “Bí Modekai, ẹni tí o ti bẹ̀rẹ̀ sí wólẹ̀ níwájú rẹ̀ bá jẹ́ Juu, o kò ní lè ṣẹgun rẹ̀, òun ni yóo ṣẹgun rẹ.” Bí wọ́n ti ń bá Hamani sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni àwọn ìwẹ̀fà ọba dé láti yára mú un lọ sí ibi àsè Ẹsita. Ọba ati Hamani lọ bá Ayaba Ẹsita jẹ àsè. Ní ọjọ́ keji, bí wọ́n ti ń mu ọtí, ọba tún bi Ẹsita pé, “Ẹsita, Ayaba, kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ, a óo ṣe é fún ọ. Kí ni ìbéèrè rẹ, gbogbo rẹ̀ ni yóo sì tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́, àní títí kan ìdajì ìjọba mi.” Ẹsita ayaba dáhùn, ó ní, “Kabiyesi, bí mo bá rí ojurere rẹ, bí ó bá sì wù ọ́, dá ẹ̀mí mi ati ti àwọn eniyan mi sí. Wọ́n ti ta èmi ati àwọn eniyan mi fún pípa, wọn ó sì pa wá run. Bí ó bá jẹ́ pé wọ́n ta tọkunrin tobinrin wa bí ẹrú lásán ni, n kì bá tí yọ ìwọ kabiyesi lẹ́nu rárá, nítorí a kò lè fi ìnira wa wé àdánù tí yóo jẹ́ ti ìwọ ọba.” Ahasu-erusi ọba bi Ẹsita Ayaba pé, “Ta ni olúwarẹ̀, níbo ni ẹni náà wà, tí ń gbèrò láti dán irú nǹkan bẹ́ẹ̀ wò?” Ẹsita bá dá a lóhùn pé, “Ọlọ̀tẹ̀ ati ọ̀tá náà ni Hamani eniyan burúkú yìí.” Ẹ̀rù ba Hamani gidigidi níwájú ọba ati ayaba. Ọba dìde kúrò ní ibi àsè náà pẹlu ibinu, ó jáde lọ sinu àgbàlá ààfin. Nígbà tí Hamani rí i pé ọba ti pinnu ibi fún òun, ó dúró lẹ́yìn láti bẹ Ẹsita Ayaba fún ẹ̀mí rẹ̀. Bí ọba ti pada wá láti inú àgbàlá sí ibi tí wọ́n ti ń mu ọtí, ó rí Hamani tí ó ṣubú sí ibi àga tí Ẹsita rọ̀gbọ̀kú sí. Ọba ní, “Ṣé yóo tún máa fi ọwọ́ pa Ayaba lára lójú mi ni, ninu ilé mi?” Ní kété tí ọba sọ̀rọ̀ yìí tán, wọ́n faṣọ bo Hamani lójú. Habona, ọ̀kan ninu àwọn ìwẹ̀fà ọba, bá sọ fún ọba pé, “Igi kan, tí ó ga ní aadọta igbọnwọ (mita 22) wà ní ilé rẹ̀, tí ó ti rì mọ́lẹ̀ láti gbé Modekai kọ́ sí, Modekai tí ó gba ẹ̀mí rẹ là.” Ọba bá ní kí wọ́n lọ gbé Hamani kọ́ sí orí rẹ̀. Wọ́n bá gbé Hamani kọ́ sí orí igi tí ó ti rì mọ́lẹ̀ fún Modekai, nígbà náà ni inú ọba tó rọ̀. Ní ọjọ́ náà gan-an ni ọba Ahasu-erusi fún Ẹsita Ayaba ní ilé Hamani, ọ̀tá àwọn Juu. Ẹsita wá sọ fún ọba pé eniyan òun ni Modekai. Láti ìgbà náà ni ọba sì ti mú Modekai wá siwaju rẹ̀. Ọba mú òrùka tí ó gbà lọ́wọ́ Hamani, ó fi bọ Modekai lọ́wọ́. Ẹsita sì fi Modekai ṣe olórí ilé Hamani. Ẹsita tún bẹ ọba, ó wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì bẹ̀ ẹ́ pẹlu omijé, pé kí ọba yí ète burúkú tí Hamani, ará Agagi, pa láti run àwọn Juu pada. Nígbà náà ni ọba na ọ̀pá àṣẹ wúrà sí Ẹsita. Ó dìde, ó sì dúró níwájú ọba, ó ní, “Bí inú kabiyesi bá dùn sí mi, tí mo sì rí ojurere rẹ̀, bí ó bá fẹ́ràn mi, tí ọ̀rọ̀ náà bá tọ́ lójú rẹ̀, jẹ́ kí ìwé àṣẹ kan ti ọ̀dọ̀ ọba jáde, láti yí ète burúkú tí Hamani, ọmọ Hamedata, ará Agagi, pa pada, àní ète tí ó pa láti run gbogbo àwọn Juu tí wọ́n wà ní ìjọba rẹ̀. Mo ṣe lè rí jamba tí ń bọ̀, tabi ìparun tí ń bọ̀ sórí àwọn eniyan mi, kí n sì dákẹ́?” Ahasu-erusi ọba dá Ẹsita Ayaba ati Modekai Juu lóhùn pé, “Mo ti so Hamani kọ́ sórí igi, nítorí ète tí ó pa lórí àwọn Juu, mo sì ti fún Ẹsita ní ilé rẹ̀. Kọ ohunkohun tí ó bá wù ọ́ nípa àwọn Juu ní orúkọ ọba, kí o sì fi òrùka ọba tẹ̀ ẹ́ bí èdìdì. Nítorí pé òfin tí a bá kọ ní orúkọ ọba, tí ó sì ní èdìdì ọba, ẹnikẹ́ni kò lè yí i pada mọ́.” Ọjọ́ kẹtalelogun oṣù kẹta, tíí ṣe oṣù Sifani ni Modekai pe àwọn akọ̀wé ọba, wọ́n sì kọ òfin sílẹ̀ nípa àwọn Juu gẹ́gẹ́ bí Modekai ti sọ fún wọn. Wọ́n fi ranṣẹ sí àwọn baálẹ̀ agbègbè, àwọn gomina, ati àwọn olórí àwọn agbègbè, láti India títí dé Etiopia, gbogbo wọn jẹ́ agbègbè mẹtadinlaadoje (127). Wọ́n kọ ọ́ sí agbègbè kọ̀ọ̀kan ati ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn, wọ́n sì kọ sí àwọn Juu náà ní èdè wọn. Wọ́n kọ ìwé náà ní orúkọ Ahasu-erusi ọba, wọ́n sì fi òrùka ọba tẹ̀ ẹ́ bí èdìdì. Wọ́n fi rán àwọn iranṣẹ tí wọn ń gun àwọn ẹṣin tí wọ́n lè sáré dáradára, àwọn ẹṣin tí wọn ń lò fún iṣẹ́ ọba, àwọn tí wọ́n ń bọ́ fún ìlò ọba. Òfin náà fún àwọn Juu ní àṣẹ láti kó ara wọn jọ, láti gba ara wọn sílẹ̀, ati láti run orílẹ̀-èdè tabi ìgbèríko tí ó bá dojú ìjà kọ wọ́n, ati àwọn ọmọ wọn, ati àwọn obinrin wọn. Wọ́n lè run ọ̀tá wọn láì ku ẹnìkan, kí wọ́n sì gba gbogbo ìní wọn. Àṣẹ yìí gbọdọ̀ múlẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ Pasia, ní ọjọ́ tí wọ́n yàn láti pa gbogbo àwọn Juu, ní ọjọ́ kẹtala oṣù kejila, tíí ṣe oṣù Adari. Àkọsílẹ̀ yìí di òfin fún gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèríko, kí àwọn Juu baà lè múra láti gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá wọn ní ọjọ́ náà. Pẹlu àṣẹ ọba, àwọn iranṣẹ gun àwọn ẹṣin ọba, wọ́n sì yára lọ. Wọ́n pa àṣẹ náà ní Susa tíí ṣe olú-ìlú. Modekai jáde ní ààfin ninu aṣọ ọba aláwọ̀ aró ati funfun pẹlu adé wúrà ńlá. Ó wọ aṣọ ìlékè aláwọ̀ elése-àlùkò, ìlú Susa sì ń hó fún ayọ̀. Àwọn Juu sì ní ìmọ́lẹ̀ ati inú dídùn, ayọ̀ ati ọlá. Ní gbogbo agbègbè, ati ní àwọn ìlú tí ìkéde yìí dé, ìdùnnú ati ayọ̀ kún inú àwọn Juu, wọ́n se àsè pẹlu ayẹyẹ, wọ́n sì gba ìsinmi. Àwọn ẹ̀yà mìíràn sọ ara wọn di Juu, nítorí pé ẹ̀rù àwọn Juu ń bà wọ́n. Ní ọjọ́ kẹtala oṣù Adari tíí ṣe oṣù kejila, nígbà tí wọ́n ń múra láti ṣe ohun tí òfin ọba wí, ní ọjọ́ tí àwọn ọ̀tá rò pé ọwọ́ wọn yóo tẹ àwọn Juu, ṣugbọn, tí ó jẹ́ ọjọ́ tí àwọn Juu ṣẹgun àwọn ọ̀tá wọn; àwọn Juu péjọ ninu àwọn ìlú wọn ní àwọn ìgbèríko ilẹ̀ Ahasu-erusi ọba, wọ́n múra láti bá àwọn tí wọ́n fẹ́ pa wọ́n run jà. Kò sí ẹni tí ó lè kò wọ́n lójú nítorí pé gbogbo àwọn eniyan ni wọ́n ń bẹ̀rù wọn. Gbogbo àwọn olórí àwọn agbègbè, àwọn baálẹ̀, àwọn gomina ati àwọn aláṣẹ ọba ran àwọn Juu lọ́wọ́, nítorí pé ẹ̀rù Modekai ń bà wọ́n. Modekai di eniyan pataki ní ààfin; òkìkí rẹ̀ kàn dé gbogbo agbègbè, agbára rẹ̀ sì ń pọ̀ sí i. Àwọn Juu fi idà pa àwọn ọ̀tá wọn, wọ́n pa wọ́n run. Ohun tí ó wù wọ́n ni wọ́n ṣe sí àwọn tí wọ́n kórìíra wọn. Ní ìlú Susa nìkan, àwọn Juu pa ẹẹdẹgbẹta (500) eniyan. Wọ́n sì pa Paṣandata, Dalifoni, Asipata, Porata, Adalia, Aridata, Pamaṣita, Arisai, Aridai ati Faisata. Àwọn mẹ́wẹ̀ẹ̀wá jẹ́ ọmọ Hamani, ọmọ Hamedata, ọ̀tá àwọn Juu, ṣugbọn wọn kò fọwọ́ kan àwọn ẹrù wọn. Ní ọjọ́ náà, wọ́n mú ìròyìn iye àwọn tí wọ́n pa ní Susa wá fún ọba. Ọba sọ fún Ẹsita Ayaba pé, “Àwọn Juu ti pa ẹẹdẹgbẹta (500) ọkunrin ati àwọn ọmọ Hamani mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ní Susa. Kí ni àwọn Juu tí wọ́n wà ní àwọn agbègbè ṣe? Nisinsinyii, kí ni ìbéèrè rẹ? A óo sì ṣe é fún ọ.” Ẹsita dáhùn pé, “Bí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, jẹ́ kí á fún àwọn Juu tí wọ́n wà ní Susa ní àṣẹ láti ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní òní sí àwọn ọ̀tá wọn ní ọ̀la, kí á sì so àwọn ọmọ Hamani mẹ́wẹ̀ẹ̀wá rọ̀ sí orí igi.” Ọba pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Àṣẹ bá jáde láti Susa, wọ́n sì so àwọn ọmọ Hamani rọ̀ sí orí igi. Ní ọjọ́ kẹrinla oṣù Adari àwọn Juu tí wọ́n wà ní Susa tún parapọ̀, wọ́n sì pa ọọdunrun (300) ọkunrin sí i. Ṣugbọn wọn kò fi ọwọ́ kan ẹrù wọn. Àwọn Juu tí wọ́n wà ní àwọn agbègbè kó ara wọn jọ láti gba ara wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn. Wọ́n pa ẹgbaa mejidinlogoji ó dín ẹgbẹrun (75,000) ninu àwọn tí wọ́n kórìíra wọn, ṣugbọn wọn kò fi ọwọ́ kan ẹrù wọn. Ní ọjọ́ kẹtala oṣù Adari ni èyí ṣẹlẹ̀. Ní ọjọ́ kẹrinla, wọ́n sinmi; ọjọ́ náà sì jẹ́ ọjọ́ àsè ati ayọ̀. Ní Susa, ọjọ́ kẹẹdogun oṣù ni wọ́n tó ṣe ayẹyẹ tiwọn. Ọjọ́ kẹtala ati ọjọ́ kẹrinla ni àwọn Juu tí wọ́n wà ní Susa pa àwọn ọ̀tá wọn, ní ọjọ́ kẹẹdogun, wọ́n sinmi, ó sì jẹ́ ọjọ́ àsè ati ayọ̀ fún wọn. Ìdí nìyí tí àwọn Juu tí wọn ń gbé àwọn agbègbè fi ya ọjọ́ kẹrinla oṣù Adari sọ́tọ̀ fún ọjọ́ àsè, tí wọn yóo máa gbé oúnjẹ fún ara wọn. Modekai kọ gbogbo nǹkan wọnyi sílẹ̀, Ó sì fi ranṣẹ sí àwọn Juu tí wọ́n wà ní gbogbo ilẹ̀ ìjọba Ahasu-erusi ọba, ati àwọn tí wọ́n wà nítòsí ati àwọn tí wọ́n wà ní òkèèrè, pé kí wọ́n ya ọjọ́ kẹrinla ati ọjọ́ kẹẹdogun oṣù Adari sọ́tọ̀, gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí àwọn Juu gba ara wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn, tí ìbànújẹ́ ati ẹ̀rù wọn di ayọ̀, tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ wọn sì di ọjọ́ àjọ̀dún. Ó pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe ọjọ́ náà ní ọjọ́ àjọ̀dún ati ayọ̀, tí wọn yóo máa gbé oúnjẹ fún ara wọn, tí wọn yóo máa fún àwọn talaka ní ẹ̀bùn. Àwọn Juu gbà láti máa ṣe bí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ati bí àṣẹ Modekai. Nítorí Hamani, ọmọ Hamedata, láti ìran Agagi, ọ̀tá àwọn Juu ti pète láti pa àwọn Juu run. Ó ti ṣẹ́ gègé, tí wọn ń pè ní Purimu, láti mọ ọjọ́ tí yóo pa àwọn Juu run patapata. Ṣugbọn nígbà tí Ẹsita lọ sọ́dọ̀ ọba, ọba kọ̀wé àṣẹ tí ó mú kí ìpinnu burúkú tí Hamani ní sí àwọn Juu pada sí orí òun tìkararẹ̀, a sì so òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ rọ̀ sórí igi. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe ọjọ́ náà ní Purimu gẹ́gẹ́ bí orúkọ Purimu, gègé tí Hamani ṣẹ́. Nítorí ìwé tí Modekai kọ ati gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn, ni àwọn Juu fi sọ ọ́ di òfin fún ara wọn, ati fún arọmọdọmọ wọn, ati fún àwọn tí wọ́n bá di Juu, pé ní àkókò rẹ̀, ní ọdọọdún, ọjọ́ mejeeji yìí gbọdọ̀ jẹ́ ọjọ́ àsè, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Modekai, ati pé kí wọ́n máa ranti àwọn ọjọ́ wọnyi, kí wọ́n sì máa pa wọ́n mọ́ láti ìrandíran, ní gbogbo ìdílé, ní gbogbo agbègbè ati ìlú. Àwọn ọjọ́ Purimu wọnyi kò gbọdọ̀ yẹ̀ láàrin àwọn Juu, bẹ́ẹ̀ ni ìrántí wọn kò gbọdọ̀ parun láàrin arọmọdọmọ wọn. Ẹsita Ayaba, ọmọbinrin Abihaili, ati Modekai, tíí ṣe Juu kọ ìwé láti fi ìdí ìwé keji nípa Purimu múlẹ̀. Wọ́n kọ ìwé sí gbogbo àwọn Juu ní gbogbo agbègbè mẹtẹẹtadinlaadoje (127) tí ó wà ninu ìjọba Ahasu-erusi. Ìwé náà kún fún ọ̀rọ̀ alaafia ati òtítọ́, pé wọn kò gbọdọ̀ gbàgbé láti máa pa àwọn ọjọ́ Purimu mọ́ ní àkókò wọn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Modekai ati Ẹsita Ayaba pa fún àwọn Juu, ati irú ìlànà tí wọ́n là sílẹ̀ fún ara wọn ati arọmọdọmọ wọn, nípa ààwẹ̀ ati ẹkún wọn. Àṣẹ tí Ẹsita pa fi ìdí àjọ̀dún Purimu múlẹ̀, wọ́n sì kọ ọ́ sílẹ̀. Ọba Ahasu-erusi pàṣẹ pé kí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jìnnà ati àwọn tí wọn ń gbé etíkun máa san owó orí. Gbogbo iṣẹ́ agbára ati ipá rẹ̀, ati bí ó ṣe gbé Modekai ga sí ipò ọlá, ni a kọ sinu ìwé ìtàn àwọn ọba Media ati ti Pasia. Modekai tíí ṣe Juu ni igbákejì sí Ahasu-erusi ọba. Ó tóbi, ó sì níyì pupọ láàrin àwọn Juu, nítorí pé ó ń wá ire àwọn eniyan rẹ̀, ó sì ń sọ̀rọ̀ alaafia fún gbogbo wọn. Ọkunrin kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jobu; ó ń gbé ilẹ̀ Usi, ó jẹ́ olódodo ati olóòótọ́ eniyan, ó bẹ̀rù Ọlọrun, ó sì kórìíra ìwà burúkú. Ó bí ọmọkunrin meje ati ọmọbinrin mẹta. Ó ní ẹẹdẹgbaarin (7,000) aguntan, ẹgbẹẹdogun (3,000) ràkúnmí, ẹẹdẹgbẹta (500) àjàgà mààlúù, ẹẹdẹgbẹta (500) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati ọpọlọpọ iranṣẹ; òun ni ó lọ́lá jùlọ ninu gbogbo àwọn ará ìlà oòrùn. Àwọn ọmọ rẹ̀ a máa lọ jẹ àsè ninu ilé ara wọn. Olukuluku wọn ní ọjọ́ àsè tirẹ̀, wọn a sì máa pe àwọn arabinrin wọn wá sí ilé láti bá wọn jẹ àsè. Nígbà tí wọ́n bá se àsè náà kárí tán, Jobu yóo ranṣẹ sí wọn láti rú ẹbọ ìwẹ̀nùmọ́ fún wọn. Ní àárọ̀ kutukutu, yóo dìde yóo rú ẹbọ sísun fún olukuluku wọn, yóo wí pé, “Bóyá àwọn ọmọ mi ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti bú Ọlọrun ninu ọkàn wọn.” Bẹ́ẹ̀ ni Jobu máa ń ṣe ní gbogbo ìgbà. Ní ọjọ́ kan, àwọn ọmọ Ọlọrun wá láti fi ara wọn hàn níwájú OLUWA. Satani náà wà láàrin wọn. OLUWA bi Satani pé, “Níbo ni o ti ń bọ̀?” Satani dá OLUWA lóhùn pé, “Mò ń lọ sókè sódò káàkiri gbogbo ayé.” OLUWA tún bi í pé, “Ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí Jobu, iranṣẹ mi, pé kò sí ẹni tí ó jẹ́ olóòótọ́ ati eniyan rere bíi rẹ̀ ní gbogbo ayé, ati pé ó bẹ̀rù èmi OLUWA, ó sì kórìíra ìwà burúkú?” Satani dáhùn pé, “Ṣé lásán ni Jobu bẹ̀rù ìwọ Ọlọrun ni? Ṣebí nígbà gbogbo ni ò ń dáàbò bo òun ati àwọn ará ilé rẹ̀, ati gbogbo ohun tí ó ní. Ò ń bukun iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, o sì sọ ohun ìní rẹ̀ di pupọ. Ǹjẹ́, ìwọ mú gbogbo nǹkan wọnyi kúrò wò, o óo rí i pé yóo sọ̀rọ̀ àfojúdi sí ọ lójú ara rẹ.” OLUWA dá Satani lóhùn pé, “Ó dára, ohun gbogbo tí ó ní wà ní ìkáwọ́ rẹ. Ṣugbọn o kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan òun fúnra rẹ̀.” Satani bá kúrò níwájú OLUWA. Ní ọjọ́ kan nígbà tí àwọn ọmọ Jobu ń jẹ àsè ninu ilé ẹ̀gbọ́n wọn ọkunrin, tí ó jẹ́ àgbà patapata, iranṣẹ kan wá sọ́dọ̀ Jobu, ó ròyìn fún un pé, “Àwọn akọ mààlúù ń fi àjàgà wọn kọlẹ̀, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì ń jẹko nítòsí wọn; àwọn ará Sabea rí wọn, wọ́n sì kó gbogbo wọn, wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn iranṣẹ, èmi nìkan ni mo sá àsálà láti wá ròyìn fún ọ.” Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ iranṣẹ mìíràn dé, ó ní, “Iná Ọlọrun wá láti ọ̀run, ó jó àwọn aguntan ati gbogbo darandaran patapata, èmi nìkan ni mo sá àsálà láti wá ròyìn fún ọ.” Kò tíì dákẹ́ ọ̀rọ̀ tí ń sọ tí iranṣẹ mìíràn fi tún dé, ó ní, “Àwọn ẹgbẹ́ ogun Kalidea mẹta kọlù wá, wọ́n kó gbogbo ràkúnmí wa lọ, wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ, èmi nìkan ni mo sá àsálà láti wá ròyìn fún ọ.” Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ iranṣẹ mìíràn dé, ó ní, “Bí àwọn ọmọ rẹ tí ń jẹ àsè ninu ilé ẹ̀gbọ́n wọn àgbà, ìjì líle kan fẹ́ la àṣálẹ̀ kọjá, ó fẹ́ lu ilé náà, ó wó, ó sì pa gbogbo wọn, èmi nìkan ni mo sá àsálà láti wá ròyìn fún ọ.” Jobu bá dìde, ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn; ó fá orí rẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó sì sin OLUWA. Ó ní, “Ìhòòhò ni wọ́n bí mi, ìhòòhò ni n óo sì pada lọ. OLUWA níí fún ni ní nǹkan, OLUWA náà ní í sì í gbà á pada, ìyìn ni fún orúkọ OLUWA.” Ninu gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ yìí, Jobu kò dẹ́ṣẹ̀, kò sì dá Ọlọrun lẹ́bi. Nígbà tí ó tún yá tí àwọn ọmọ Ọlọrun wá farahàn níwájú OLUWA, Satani náà wà láàrin wọn. OLUWA tún bi Satani pé, “Níbo ni o ti ń bọ̀?” Satani dá OLUWA lóhùn pé, “Mò ń lọ sókè sódò káàkiri gbogbo ayé.” Ọlọrun tún bi í pé, “Ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí Jobu, iranṣẹ mi, pé kò sí olóòótọ́ ati eniyan rere bíi rẹ̀ ní gbogbo ayé. Ó bẹ̀rù OLUWA, ó sì kórìíra ìwà burúkú, ó dúró ṣinṣin ninu ìwà òtítọ́ rẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o dẹ mí sí i láti pa á run láìnídìí.” Satani dá OLUWA lóhùn pé, “Ohun gbogbo ni eniyan lè fi sílẹ̀ láti gba ẹ̀mí rẹ̀ là. Ìwọ fi ọwọ́ kan ara ati eegun rẹ̀ wò, bí kò bá ní sọ̀rọ̀ àfojúdi sí ọ lójú ara rẹ.” OLUWA bá ní, “Ó wà ní ìkáwọ́ rẹ, ṣugbọn o kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ẹ̀mí rẹ̀.” Satani bá lọ kúrò níwájú OLUWA, ó sì da oówo bo Jobu lára, láti àtẹ́lẹsẹ̀ títí dé orí. Jobu ń fi àpáàdì họ ara, ó sì jókòó sinu eérú. Iyawo Jobu bá sọ fún un pé, “Orí òtítọ́ inú rẹ ni o tún wà sibẹ? Fi Ọlọrun bú, kí o kú.” Ṣugbọn ó dáhùn pé, “Ò ń sọ̀rọ̀ bí ìgbà tí ọ̀kan ninu àwọn aláìmòye obinrin bá ń sọ̀rọ̀. Ǹjẹ́ eniyan lè gba ire lọ́wọ́ Ọlọrun kí ó má gba ibi?” Ninu gbogbo nǹkan wọnyi, Jobu kò dẹ́ṣẹ̀ rárá ninu ọ̀rọ̀ tí ó sọ. Nígbà tí Elifasi ará Temani, Bilidadi ará Ṣuha ati Sofari ará Naama, àwọn ọ̀rẹ́ Jobu mẹta, gbọ́ nípa ìyọnu tí ó dé bá Jobu, wọ́n wá láti kí i, ati láti tù ú ninu. Nígbà tí wọ́n rí Jobu ní ọ̀ọ́kán, wọn kò mọ̀ ọ́n mọ́. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n súnmọ́ ọn tí wọ́n mọ̀ pé òun ni, wọ́n bú sẹ́kún, wọ́n fa aṣọ wọn ya, wọ́n sì ku eruku sórí. Wọ́n jókòó ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀ pẹlu rẹ̀ fún ọjọ́ meje, tọ̀sán-tòru, láìsọ nǹkankan, nítorí pé wọ́n rí i bí ìrora náà ti pọ̀ tó. Nígbà tí ó yá, Jobu bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, ó fi ọjọ́ ìbí ara rẹ̀ bú. Ó ní: “Ègún ni fún ọjọ́ tí wọ́n bí mi, ati alẹ́ tí wọ́n lóyún mi. Jẹ́ kí ọjọ́ náà ṣókùnkùn biribiri! Kí Ọlọrun má ṣe ka ọjọ́ náà sí, kí ìmọ́lẹ̀ má ṣe tàn sí i mọ́. Ṣe é ní ọjọ́ ìṣúdudu, ati òkùnkùn biribiri. Kí ìkùukùu ṣíji bò ó, kí òkùnkùn sì dẹ́rù bà á. Kí òkùnkùn ṣú bo alẹ́ ọjọ́ náà biribiri, kí á yọ ọ́ kúrò ninu àwọn ọjọ́ tí ó wà ninu ọdún, kí á má sì ṣe kà á kún àwọn ọjọ́ tí wọ́n wà ninu oṣù. Kí alẹ́ ọjọ́ náà di òfo, kí á má ṣe gbọ́ ìró ayọ̀ ninu rẹ̀ mọ́. Kí àwọn tí wọ́n ń fi ọjọ́ gégùn-ún fi gégùn-ún, àní àwọn tí wọ́n lè fi àṣẹ rú Lefiatani sókè. Kí ìràwọ̀ òwúrọ̀ rẹ̀ ṣókùnkùn, kí ìrètí rẹ̀ fún ìmọ́lẹ̀ àfẹ̀mọ́júmọ́ já sí òfo, kí ó má rí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ mọ́; nítorí pé kò sé inú ìyá mi nígbà tí ó fẹ́ bí mi, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mú ibi kúrò lọ́nà mi. “Kí ló dé tí n kò kú nígbà tí ìyá mi ń rọbí lọ́wọ́, tí ó fẹ́ bí mi, tabi kí n kú, lẹsẹkẹsẹ tí wọ́n bí mi? Kí ló dé tí ìyá mi gbé mi lẹ́sẹ̀? Kí ló dé tí ó fi fún mi lọ́mú? Ǹ bá ti dùbúlẹ̀, ǹ bá ti dákẹ́ jẹ́ẹ́; ǹ bá ti sùn, ǹ bá sì ti máa sinmi pẹlu àwọn ọba ati àwọn ìgbìmọ̀ àgbáyé, tí wọ́n ti sùn, àwọn tí wọ́n tún àlàpà kọ́ fún ara wọn; tabi pẹlu àwọn ọmọ aládé tí wọ́n ní wúrà, tí fadaka sì kún ilé wọn. Tabi kí n rí bí ọmọ tí a bí ní ọjọ́ àìpé, tí a bò mọ́lẹ̀ láì tíì lajú sáyé. Níbi tí àwọn oníṣẹ́ ibi kò ti lágbára mọ́, tí àwọn tí gbogbo nǹkan ti sú gbé ń sinmi. Níbẹ̀, àwọn ẹlẹ́wọ̀n ń gbé pọ̀ pẹlu ìrọ̀rùn, wọn kò sì gbọ́ ohùn akóniṣiṣẹ́ mọ́. Àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan pataki pataki jọ wà níbẹ̀, àwọn ẹrú sì bọ́ lọ́wọ́ oluwa wọn. “Kí ló dé tí a fi ìmọ́lẹ̀ fún ẹni tí ń kérora, tí a fi ẹ̀mí fún ẹni tí inú rẹ̀ bàjẹ́; tí ó ń wá ikú, ṣugbọn tí kò rí; tí ó ń wá ikú lójú mejeeji ju ẹni tí ń wá ìṣúra tí a fi pamọ́ lọ? Àwọn tí inú wọn ìbá dùn lọpọlọpọ bí wọ́n bá rí ẹni gbé wọn sin. Kí ló dé tí a fi fi ìmọ́lẹ̀ fún ẹni tí ọ̀nà dàrú mọ́ lójú; ẹni tí Ọlọrun ti tì sinu àhámọ́? Nítorí ìmí ẹ̀dùn di oúnjẹ fún mi, ìráhùn mi sì ń tú jáde bí omi. Ohun tí mo bẹ̀rù jù ti dé bá mi, ohun tí ń fò mí láyà ti ṣẹlẹ̀ sí mi. N kò ní alaafia, bẹ́ẹ̀ ni ara kò rọ̀ mí, n kò sì ní ìsinmi, àfi ìyọnu.” Nígbà náà ni Elifasi, ará Temani, dá Jobu lóhùn, ó ní: “Bí eniyan bá bá ọ sọ̀rọ̀, ṣé kò ní bí ọ ninu? Àbí eniyan ha lè dákẹ́ bí? O ti kọ́ ọpọlọpọ eniyan, o ti fún aláìlera lókun. O ti fi ọ̀rọ̀ gbé àwọn tí wọn ń ṣubú ró, ọ̀rọ̀ rẹ ti fún orúnkún tí ń yẹ̀ lọ lágbára. Ṣugbọn nisinsinyii tí ọ̀rọ̀ kàn ọ́, o kò ní sùúrù; Ó dé bá ọ, ìdààmú bá ọ. Ṣé ìbẹ̀rù Ọlọrun kò tó ìgboyà fún ọ? Àbí ìwà òdodo rẹ kò fún ọ ní ìrètí? “Ìwọ náà ronú wò, ṣé aláìṣẹ̀ kan ṣègbé rí? Tabi olódodo kan parun rí? Bí èmi ti rí i sí ni pé, ẹni tí ó kọ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ ebè, tí ó sì gbin wahala, yóo kórè ìyọnu. Èémí Ọlọrun níí pa wọ́n run, ninu ibinu rẹ̀, wọ́n a sì ṣègbé. Ọlọrun fi òpin sí igbe kinniun, ati bíbú tí kinniun ń bú ramúramù, ó sì wọ́ àwọn ẹgbọ̀rọ̀ kinniun léyín. Kinniun alágbára a máa kú, nítorí àìrí ẹran pa jẹ, àwọn ọmọ abo kinniun a sì fọ́nká. “Nisinsinyii wọ́n fọ̀rọ̀ kan tó mi létí mo gbọ́ wúyẹ́-wúyẹ́ rẹ̀. Ninu ìran lóru, nígbà tí àwọn eniyan sùn fọnfọn, ìbẹ̀rùbojo mú mi, gbogbo ara mi sì ń gbọ̀n rìrì. Ẹ̀mí kan kọjá fìrí níwájú mi, gbogbo irun ara mi sì dìde. Ó dúró jẹ́ẹ́, ṣugbọn n kò mọ̀ bí ó ti rí. Mo ṣá rí kinní kan tí ó dúró; gbogbo nǹkan parọ́rọ́, nígbà náà ni mo gbọ́ ohùn kan tí ó wí pé, ‘Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè jẹ́ olódodo níwájú Ọlọrun? Tabi kí eniyan jẹ́ mímọ́ níwájú Ẹlẹ́dàá rẹ̀? Nígbà tí ó jẹ́ pé, Ọlọrun kò gbẹ́kẹ̀lé àwọn iranṣẹ rẹ̀, a sì máa bá àṣìṣe lọ́wọ́ àwọn angẹli rẹ̀; mélòó mélòó wá ni eniyan tí a fi amọ̀ mọ, tí ìpìlẹ̀ wọn jẹ́ erùpẹ̀, tí a lè pa bíi kòkòrò lásánlàsàn. Eniyan lè wà láàyè ní òwúrọ̀ kí ó kú kí ó tó di ọjọ́ alẹ́, wọn a parun títí lae láìsí ẹni tí yóo bìkítà. Bí a bá gba gbogbo ohun tí wọ́n fẹ̀mí tẹ̀, ṣé wọn kò ní kú bí aláìgbọ́n?’ “Pe ẹnìkan nisinsinyii; ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni dá ọ lóhùn? Ẹni mímọ́ wo ni o lè tọ̀ lọ? Dájúdájú ibinu a máa pa òmùgọ̀, owú jíjẹ a sì máa pa aláìmọ̀kan. Mo ti rí òmùgọ̀ tí ó fìdí múlẹ̀, ṣugbọn lójijì, ibùgbé rẹ̀ di ìfibú. Kò sí ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n di àtẹ̀mọ́lẹ̀ ni ẹnubodè, kò sì sí ẹni tí ó lè gbà wọ́n là. Àwọn tí ebi ń pa níí jẹ ìkórè oko rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ààrin ẹ̀gún ni ó ti mú un jáde, àwọn olójúkòkòrò a sì máa wá ohun ìní rẹ̀ kiri. Ìṣòro kì í hù láti inú erùpẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìyọnu kì í ti inú ilẹ̀ jáde. A bí eniyan sinu wahala bí ẹ̀ta iná tí ń ta sókè. “Ní tèmi, n óo máa wá OLUWA, n óo fọ̀rọ̀ mi lé Ọlọrun lọ́wọ́; ẹni tíí ṣe ohun ńlá tí eniyan kò lè rídìí, ati àwọn ohun ìyanu tí kò lóǹkà. A máa rọ òjò sórí ilẹ̀, a sì máa bomi rin oko. A máa gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ga, a sì máa pa àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ mọ́. A máa da ète àwọn alárèékérekè rú, kí wọn má baà lè yọrí ètekéte wọn. Ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n ninu àrékérekè wọn; ó sì mú ète àwọn ẹlẹ́tàn wá sópin. Òkùnkùn bò wọ́n ní ọ̀sán gangan, wọ́n ń fọwọ́ tálẹ̀ lọ́sàn-án bí ẹnipé òru ni. Ṣugbọn Ọlọrun gba aláìníbaba kúrò lọ́wọ́ wọn, ó gba àwọn aláìní kúrò lọ́wọ́ àwọn alágbára. Nítorí náà, ìrètí ń bẹ fún talaka, a sì pa eniyan burúkú lẹ́nu mọ́. “Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí Ọlọrun bá bá wí, nítorí náà, má ṣe kẹ́gàn ìbáwí Olodumare. Ó ń ṣá ni lọ́gbẹ́, ṣugbọn ó tún ń dí ọgbẹ́ ẹni. Ó ń pa ni lára, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ ló tún fi ń ṣe ìwòsàn. Yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ ìnira lọpọlọpọ ìgbà, bí ibi ń ṣubú lu ara wọn, kò ní dé ọ̀dọ̀ rẹ. Ní àkókò ìyàn, yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ ikú. Ní àkókò ogun, yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ idà. Yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́gàn, o kò ní bẹ̀rù nígbà tí ìparun bá dé. Ninu ìparun ati ìyàn, o óo máa rẹ́rìn-ín, o kò ní bẹ̀rù àwọn ẹranko ìgbẹ́. O kò ní kan àwọn òkúta ninu oko rẹ, àwọn ẹranko igbó yóo wà ní alaafia pẹlu rẹ. O óo máa gbé ilé rẹ ní àìséwu. Nígbà tí o bá ka ẹran ọ̀sìn rẹ, kò ní dín kan. Àwọn arọmọdọmọ rẹ yóo pọ̀, bí ewéko ninu pápá oko. O óo di arúgbó kí o tó kú, gẹ́gẹ́ bí ọkà tií gbó kí á tó kó o wá síbi ìpakà. Wò ó! A ti wádìí àwọn nǹkan wọnyi, òtítọ́ ni wọ́n. Gbọ́, kí o sì mọ̀ pé fún ire ara rẹ ni.” Jobu bá dáhùn pé, “Bí ó bá ṣeéṣe láti wọn ìbànújẹ́ mi, tí a bá sì le gbé ìdààmú mi lé orí ìwọ̀n, ìbá wúwo ju yanrìn etí òkun lọ. Ìdí nìyí tí mo fi ń fi ìtara sọ̀rọ̀. Ọfà Olodumare wọ̀ mí lára, oró rẹ̀ sì mú mi. Ọlọrun kó ìpayà bá mi. Ǹjẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó a máa ké tí ó bá rí koríko jẹ? Àbí mààlúù a máa dún tí ó bá ń wo oúnjẹ rẹ̀ nílẹ̀? Ǹjẹ́ ohun tí kò dùn ṣe é jẹ láì fi iyọ̀ sí i? Tabi, adùn wo ní ń bẹ ninu funfun ẹyin? Irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀ kì í wù mí í jẹ, Ìríra ni jíjẹ rẹ̀ jẹ́ fún mi. “Ìbá ti dára tó, kí Ọlọrun mú ìbéèrè mi ṣẹ, kí ó fún mi ní ohun tí ọkàn mi ń fẹ́. Àní, kí ó wó mi mọ́lẹ̀, kí ó mú mi, kí ó pa mí dànù. Yóo jẹ́ ìtùnú fún mi; n óo sì láyọ̀ ninu ọpọlọpọ ìrora, nítorí pé n kò sẹ́ ọ̀rọ̀ Ẹni Mímọ́. Agbára wo ni mo ní, tí mo fi lè tún máa wà láàyè? Kí sì ni ìrètí mi, tí n óo fi tún máa ní sùúrù? Agbára mi ha rí bí ti òkúta bí? Àbí ẹran ara mi jẹ́ idẹ? Nítòótọ́, n kò ní agbára mọ́, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì ní olùrànlọ́wọ́. “Ẹni tí ó bá kọ̀ tí kò ṣàánú ọ̀rẹ́ rẹ̀ kò ní ìbẹ̀rù Olodumare. Ṣugbọn, ẹ̀yin arakunrin mi, ẹlẹ́tàn ni yín, bíi odò àgbàrá tí ó yára kún, tí ó sì tún yára gbẹ, tí yìnyín bo odò náà tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣókùnkùn, tí yìnyín ńláńlá sì farapamọ́ sibẹ, ṣugbọn ní àkókò ooru, wọn a yọ́, bí ilẹ̀ bá ti gbóná, wọn a sì gbẹ. Àwọn oníṣòwò tí ń lo ràkúnmí yà kúrò ní ọ̀nà wọn, wọ́n ń wá omi kiri wọ́n kiri títí wọ́n fi ṣègbé ninu aṣálẹ̀. Àwọn oníṣòwò Temani ń wò rá rà rá, àwọn ọ̀wọ́ èrò Ṣeba sì dúró pẹlu ìrètí. Ìrètí wọn di òfo nítorí wọ́n ní ìdánilójú. Wọ́n dé ibi tí odò wà tẹ́lẹ̀, ṣugbọn òfo ni wọ́n bá. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ rí sí mi nisinsinyii. Ẹ rí ìdààmú mi, ẹ̀rù bà yín. Ǹjẹ́ mo tọrọ ẹ̀bùn lọ́wọ́ yín? Tabi mo bẹ̀ yín pé kí ẹ mú ninu owó yín, kí ẹ fi san àbẹ̀tẹ́lẹ̀ nítorí mi? Ǹjẹ́ mo bẹ̀ yín pé kí ẹ gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá; tabi pé kí ẹ rà mí pada kúrò lọ́wọ́ aninilára? “Ó dára, mo gbọ́, ẹ wá kọ́ mi, ẹ ṣàlàyé ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ṣẹ̀ fún mi; n óo sì dákẹ́ n óo tẹ́tí sílẹ̀. Lóòótọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ ní agbára, ṣugbọn kí ni ẹ̀ ń bá mi wí lé lórí. Ẹ rò pé mò ń fi ọ̀rọ̀ ṣòfò lásán ni? Kí ni ẹ̀ ń dásí ọ̀rọ̀ èmi onírora sí? Ẹ tilẹ̀ lè ṣẹ́ gègé lórí ọmọ òrukàn, ẹ sì lè díye lé ọ̀rẹ́ yín. “Ẹ gbọ́, ẹ wò mí dáradára, nítorí n kò ní purọ́ níwájú yín. Mo bẹ̀ yín, ẹ dúró bẹ́ẹ̀, kí ẹ má baà ṣẹ̀. Ẹ dúró bẹ́ẹ̀, nítorí n kò lẹ́bi. Ṣé ẹ rò pé mò ń parọ́ ni? Àbí n kò mọ nǹkan burúkú yàtọ̀? “Ìgbésí ayé eniyan le koko, ọjọ́ ayé rẹ̀ sì dàbí ti alágbàṣe. Ó dàbí ẹrú tí ń wá ìbòòji kiri ati bí alágbàṣe tí ń dúró de owó iṣẹ́ rẹ̀. Òfo ni ọ̀rọ̀ mi látoṣù-dóṣù, ìbànújẹ́ ní sì ń dé bá mi láti ọjọ́ dé ọjọ́ Bí mo bá sùn lóru, n óo máa ronú pé, ‘Ìgbà wo ni ilẹ̀ óo mọ́ tí n óo dìde?’ Òru a gùn bí ẹni pé ojúmọ́ kò ní mọ́ mọ́, ma wá máa yí síhìn-ín, sọ́hùn-ún, títí ilẹ̀ yóo fi mọ́. Gbogbo ara mi kún fún kòkòrò, ati ìdọ̀tí, gbogbo ara mi yi, ó sì di egbò. Ọjọ́ ayé mi ń sáré ju ọ̀kọ̀ ìhunṣọ lọ, Ó sì ń lọ sópin láìní ìrètí. “Ọlọrun, ranti pé afẹ́fẹ́ lásán ni mo jẹ́, ati pé ojú mi kò ní rí ohun rere mọ́. Ojú ẹni tí ó rí mi nisinsinyii kò ní rí mi mọ́; níṣojú yín báyìí ni n óo fi parẹ́. Bí ìkùukùu tíí parẹ́ tí a kì í rí i mọ́, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀mí tí ó lọ sí ipò òkú rí, kò ní pada mọ́. Kò ní pada sí ilé rẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni ibùjókòó rẹ̀ kò ní mọ̀ ọ́n mọ́. “Nítorí náà, n kò ní dákẹ́; n óo sọ ìrora ọkàn mi; n óo tú ìbànújẹ́ mi jáde. Ṣé òkun ni mí ni, tabi erinmi, tí ẹ fi yan olùṣọ́ tì mí? Nígbà tí mo wí pé, ‘Ibùsùn mi yóo tù mí lára, ìjókòó mi yóo sì mú kí ara tù mí ninu ìráhùn mi’. Nígbà náà ni ẹ̀yin tún wá fi àlá yín dẹ́rù bà mí, tí ẹ sì fi ìran pá mi láyà, kí n lè fara mọ́ ọn pé ó sàn kí á lọ́ mi lọ́rùn pa, kí n sì lè yan ikú dípò pé kí n wà láàyè. Ayé sú mi, n kò ní wà láàyè títí lae. Ẹ fi mí sílẹ̀, nítorí ọjọ́ ayé mi dàbí èémí lásán. Kí ni eniyan jẹ́, tí o fi gbé e ga, tí o sì fi ń náání rẹ̀; tí ò ń bẹ̀ ẹ́ wò láràárọ̀, tí o sì ń dán an wò nígbà gbogbo? Yóo ti pẹ́ tó kí ẹ tó mójú kúrò lára mi? Kí ẹ tó fi mí lọ́rùn sílẹ̀ kí n rí ààyè dá itọ́ mì? Bí mo bá ṣẹ̀, kí ni ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ṣẹ̀ yín, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń ṣọ́ mi? Kí ló dé tí ẹ fi dójú lé mi, tí mo di ẹrù lọ́rùn yín? Kí ló dé tí ẹ kò lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí kí ẹ sì fojú fo àìdára mi? Láìpẹ́ n óo lọ sinu ibojì. Ẹ óo wá mi, ṣugbọn n kò ní sí mọ́.” Bilidadi ará Ṣuha dáhùn pé, “O óo ti sọ irú ọ̀rọ̀ wọnyi pẹ́ tó, tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ yóo sì dàbí afẹ́fẹ́ líle? Ṣé Ọlọrun a máa yí ìdájọ́ po? Ṣé Olodumare a máa yí òdodo pada? Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ọmọ rẹ dẹ́ṣẹ̀ ni, ó ti jẹ wọ́n níyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ṣugbọn bí o bá wá Ọlọrun, tí o sì sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ fún Olodumare; tí o bá jẹ́ ẹni mímọ́ ati olóòótọ́, dájúdájú OLUWA yóo dìde, yóo ràn ọ́ lọ́wọ́, yóo sì fi ibùgbé rere san ẹ̀san fún ọ. Díẹ̀ ni ọrọ̀ tí o ní tẹ́lẹ̀ yóo jẹ́ lára ohun tí Ọlọrun yóo fún ọ ní ọjọ́ iwájú. “Mo bẹ̀ ọ́, lọ wádìí nípa ìgbà àtijọ́, kí o ṣe akiyesi ìrírí àwọn baba wa. Nítorí ọmọde ni wá, a kò mọ nǹkankan, ọjọ́ ayé wa sì dàbí òjìji. Àwọn ni wọn óo kọ́ ọ, tí wọn óo bá ọ sọ̀rọ̀, tí wọn óo sì fún ọ ní ìmọ̀ràn ninu òye wọn. “Ṣé koríko etídò le hù níbi tí kò sí àbàtà? Tabi kí èèsún hù níbi tí kò sí omi? Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ nígbà tí ó bá ń tanná lọ́wọ́, yóo rọ ṣáájú gbogbo ewéko, láìjẹ́ pé ẹnikẹ́ni gé e lulẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ ẹni tí ó gbàgbé Ọlọrun rí; ìrètí ẹni tí kò mọ Ọlọrun yóo parun. Igbẹkẹle rẹ̀ já sí asán, ìmúlẹ̀mófo ni, bí òwú aláǹtakùn. Ó farati ilé rẹ̀, ṣugbọn kò le gbà á dúró. Ó dì í mú, ṣugbọn kò lè mú un dúró. Kí oòrùn tó yọ, ẹni ibi a máa tutù yọ̀yọ̀, àwọn ẹ̀ka rẹ̀ a sì gbilẹ̀ káàkiri inú ọgbà rẹ̀. Ṣugbọn ara òkúta ni gbòǹgbò rẹ̀ rọ̀ mọ́, òun gan-an sì ń gbé ààrin àpáta. Bí wọ́n bá fà á tu kúrò ní ààyè rẹ̀, kò sí ẹni tí yóo mọ̀ pé ó wà níbẹ̀ rí. Ayọ̀ ọrọ̀ rẹ̀ kò jù báyìí lọ, àwọn mìíràn óo dìde, wọn yóo sì gba ipò rẹ̀. “Ṣugbọn Ọlọrun kò jẹ́ fi àwọn olóòótọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò jẹ́ ran ẹni ibi lọ́wọ́. Yóo tún fi ẹ̀rín kún ọ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́, ẹnu rẹ yóo kún fún ìhó ayọ̀. Ojú yóo ti àwọn ọ̀tá rẹ, ilé àwọn eniyan burúkú yóo sì parẹ́.” Jobu dáhùn pé: “Lóòótọ́, mo mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí, ṣugbọn báwo ni ẹlẹ́ran ara ṣe lè jẹ́ olódodo níwájú Ọlọrun? Bí eniyan tilẹ̀ fẹ́ bá a jiyàn, olúwarẹ̀ kò ní lè dáhùn ẹyọ kan ninu ẹgbẹrun ìbéèrè tí yóo bèèrè. Ọgbọ́n rẹ̀ jinlẹ̀, agbára rẹ̀ sì pọ̀. Ta ló tó ṣe oríkunkun sí i kí ó mú un jẹ? Ẹni tí ó ṣí àwọn òkè nídìí, ninu ibinu rẹ̀; tí wọn kò sì mọ ẹni tí ó bì wọ́n ṣubú. Ó ti ayé kúrò ní ipò rẹ̀, àwọn òpó rẹ̀ sì wárìrì. Ó pàṣẹ fún oòrùn, oòrùn kò sì yọ; ó sé àwọn ìràwọ̀ mọ́lé; òun nìkan ṣoṣo ni ó dá ojú ọ̀run tẹ́ bí aṣọ, tí ó sì tẹ ìgbì omi òkun mọ́lẹ̀. Ó dá àwọn ìràwọ̀ sójú ọ̀run: Beari, Orioni, ati Pileiadesi ati àwọn ìràwọ̀ ìhà gúsù. Ó ṣe àwọn ohun ńlá tí ó kọjá òye ẹ̀dá, ati àwọn iṣẹ́ ìyanu tí kò ní òǹkà. Ó gba ẹ̀gbẹ́ mi kọjá, n kò rí i, ó ń kọjá lọ, n kò sì mọ̀. Wò ó! Ó já àwọn ohun tí ó wù ú gbà, ta ló lè dá a dúró? Ta ló tó bi í pé, ‘Kí ni ò ń ṣe?’ “Ọlọrun kò ní dáwọ́ ibinu rẹ̀ dúró, yóo fi ẹsẹ̀ tẹ àwọn olùrànlọ́wọ́ Rahabu mọ́lẹ̀. Báwo ni mo ṣe lè bá a rojọ́? Kí ni kí n sọ? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lẹ́bi, sibẹsibẹ n kò lè dá a lóhùn. Ẹ̀bẹ̀ nìkan ni mo lè bẹ̀ fún àánú, lọ́wọ́ ẹni tí ń fi ẹ̀sùn kàn mí. Bí mo bá pè é pé kó wá gbọ́, tí ó sì dá mi lóhùn, sibẹ n kò lè gbàgbọ́ pé yóo dẹtí sílẹ̀ gbọ́rọ̀ mi. Nítorí pé ó ti fi ìjì tẹ̀ mí mọ́lẹ̀, ó sì sọ egbò mi di pupọ láìnídìí; kò ní jẹ́ kí n mí, ìbànújẹ́ ni ó fi kún ọkàn mi. Bí ó bá ṣe ti pé kí á dán agbára wò ni, agbára rẹ̀ pọ̀ tayọ! Bí ó bá sì jẹ́ pé ti ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́, ta ló lè pè é lẹ́jọ́? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lẹ́bi, sibẹsibẹ ọ̀rọ̀ ẹnu mi yóo di ẹ̀bi rù mí; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lẹ́ṣẹ̀, sibẹsibẹ yóo fihàn pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí. N kò lẹ́bi, sibẹ n kò ka ara mi kún, ayé sú mi. Kò sí ìyàtọ̀ lójú rẹ̀, nítorí náà ni mo fi wí pé, ati ẹlẹ́bi ati aláìlẹ́bi ni ó ti parun. Nígbà tí nǹkan burúkú bá ṣẹlẹ̀, tí ó já sí ikú òjijì, a máa fi aláìṣẹ̀ ṣe ẹlẹ́yà ninu ìdààmú wọn. A ti fi ayé lé àwọn ẹni ibi lọ́wọ́, ó ti di àwọn adájọ́ rẹ̀ lójú. Bí kì í bá ṣe òun Ọlọrun, ta ló tún tó bẹ́ẹ̀? “Ọjọ́ ayé mi ń sáré lọ tete, kò sí ẹyọ ọjọ́ kan tí ó dára ninu wọn. Wọ́n sáré kọjá lọ bíi koríko ojú omi, bí ẹyẹ idì tí ń fò fẹ̀ẹ̀ lọ bá ohun tí ó fẹ́ pa. Bí mo bá sọ pé kí n gbàgbé ìráhùn mi, kí n sì tújúká; kí n má ronú mọ́; ẹ̀rù ìrora mi á bẹ̀rẹ̀ sí bà mí, nítorí mo mọ̀ pé o kò ní gbà pé n kò dẹ́ṣẹ̀. Níwọ̀n ìgbà tí a ti dá mi lẹ́bi, kí ni mo tún ń ṣe wahala lásán fún? Ọṣẹ yòówù tí mo lè fi wẹ̀, kódà kí n fi omi yìnyín fọ ọwọ́, sibẹ o óo tì mí sinu kòtò ìdọ̀tí. Kódà n óo di ohun ìríra sí aṣọ ara mi. Ọlọrun kì í ṣe eniyan bíì mi, tí mo fi lè fún un lésì, tí a fi lè jọ rojọ́ ní ilé ẹjọ́. Kò sí ẹnìkẹta láàrin àwa mejeeji, tí ó lè dá wa lẹ́kun. Kí ó sọ pàṣán rẹ̀ sílẹ̀, kí ó má nà mí mọ́! Kí ìbẹ̀rù rẹ̀ má sì pá mi láyà mọ́! Kí n baà le sọ̀rọ̀ láìbẹ̀rù, nítorí mo mọ inú ara mi. “Ayé sú mi, nítorí náà n kò ní dákẹ́ ìráhùn; n óo sọ̀rọ̀ pẹlu ìbànújẹ́ ọkàn. N óo sọ fún Ọlọrun pé kí ó má dá mi lẹ́bi; kí ó sì jẹ́ kí n mọ ìdí tí ó fi ń bá mi jà. Ṣé ohun tí ó dára ni, Ọlọrun pé kí o máa ni eniyan lára, kí o kórìíra iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, kí o sì fẹ́ràn ète ẹni ibi? Ǹjẹ́ ojú rẹ dàbí ti eniyan? Ǹjẹ́ a máa rí nǹkan bí eniyan ṣe rí i? Ǹjẹ́ bí ọjọ́ ti eniyan ni ọjọ́ rẹ rí? Ǹjẹ́ ọdún rẹ rí bíi ti eniyan? Tí o fi wá ń wádìí àṣìṣe mi, tí o sì ń tanná wá ẹ̀ṣẹ̀ mi? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o mọ̀ pé n kò lẹ́bi, ati pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè gbà mí lọ́wọ́ rẹ. Ọwọ́ rẹ ni o fi dá mi, ọwọ́ kan náà ni o sì tún fẹ́ fi pa mí run. Ranti pé, amọ̀ ni o fi mọ mí, ṣé o tún fẹ́ sọ mí di erùpẹ̀ pada ni? Ṣebí ìwọ ni o dà mí bí omi wàrà, tí o sì ṣù mí pọ̀ bíi wàrà sísè? Ìwọ ni o fi awọ ati ẹran bò mí, tí o rán egungun ati iṣan mi pọ̀. O fún mi ní ìyè, o sì fi ìfẹ́ ńlá rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi, ìtọ́jú rẹ sì ti gbé ẹ̀mí mi ró. Sibẹ o pa gbogbo nǹkan wọnyi mọ́ sọ́kàn rẹ, mo mọ̀ pé èrò ọkàn rẹ ni pé, bí mo bá ṣẹ̀, o óo dójú lé mi, o kò ní jẹ́ kí n lọ láìjìyà. Bí mo bá ṣe àìdára, mo gbé, ṣugbọn bí mo ṣe dáradára, n kò lè yangàn, nítorí ìbànújẹ́ ati ìtìjú bò mí mọ́lẹ̀. Bí mo bá ṣe àṣeyọrí, o óo máa lépa mi bíi kinniun; ò ń lo agbára rẹ láti pa mí lára. O wá àwọn ẹlẹ́rìí tuntun pé kí wọ́n dojú kọ mí, O tún bẹ̀rẹ̀ sí bínú sí mi lọpọlọpọ, O mú kí ogun mìíràn dó tì mí. “Kí ló dé tí o fi mú mi jáde láti inú ìyá mi? Ìbá sàn kí n ti kú, kí ẹnikẹ́ni tó rí mi. Wọn ìbá má bí mi rárá, kí wọ́n gbé mi láti inú ìyá mi lọ sinu ibojì. Ṣebí ọjọ́ díẹ̀ ni mo níláti lò láyé? Fi mí sílẹ̀ kí n lè ní ìtura díẹ̀, kí n tó pada síbi tí mo ti wá, sí ibi òkùnkùn biribiri, ibi òkùnkùn ati ìdàrúdàpọ̀, níbi tí ìmọ́lẹ̀ ti dàbí òkùnkùn.” Sofari ará Naama dáhùn pé, “Ǹjẹ́ ó dára kí eniyan sọ ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ kalẹ̀ báyìí kí ó má sì ìdáhùn? Àbí, ṣé ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ lè mú kí á dá eniyan láre? Ṣé o rò pé ìsọkúsọ rẹ lè pa eniyan lẹ́nu mọ́ ni? Tabi pé bí o bá ń ṣe ẹlẹ́yà ẹnikẹ́ni kò lè dójútì ọ́? Nítorí o sọ pé ẹ̀kọ́ rẹ tọ̀nà, ati pé ẹni mímọ́ ni ọ́ lójú Ọlọrun. Ọlọrun ìbá ya ẹnu rẹ̀, kí ó sọ̀rọ̀ sí ọ. Kì bá jẹ́ fi àṣírí ọgbọ́n hàn ọ́, nítorí ìmọ̀ rẹ̀ pọ̀ lọpọlọpọ. Mọ̀ dájú pé ìyà tí Ọlọrun fi jẹ ọ́ kò to nǹkan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. “Ǹjẹ́ o lè wádìí àwọn ohun ìjìnlẹ̀ nípa Ọlọrun? Tabi kí o tọpinpin Olodumare? Ó ga ju ọ̀run lọ, kí lo lè ṣe sí i? Ó jìn ju isà òkú lọ, kí lo lè mọ̀ nípa rẹ̀? Ó gùn ju ayé lọ, Ó sì fẹ̀ ju òkun lọ. Tí ó bá ń kọjá lọ, tí ó sì ti eniyan mọ́lé, tí ó pe olúwarẹ̀ lẹ́jọ́, ta ló lè yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ wò? Nítorí ó mọ àwọn eniyan lásán, ṣé bí ó bá rí ẹ̀ṣẹ̀, kí ó má ṣe akiyesi rẹ̀? Ó di ìgbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bá bí ọmọ rẹ̀ ní eniyan, kí òmùgọ̀ eniyan tó gbọ́n. “Bí o bá fi ọkàn rẹ sí ohun tí ó tọ́, o óo lè nawọ́ sí i. Bí o bá ń dẹ́ṣẹ̀, má dẹ́ṣẹ̀ mọ́, má sì ṣe jẹ́ kí ìwà burúkú, wà ní ọwọ́ rẹ. Nígbà náà ni o óo tó lè fi ìgboyà gbójú sókè láìlẹ́bi; o óo wà láìléwu, o kò sì ní bẹ̀rù. O óo gbàgbé àwọn ìyọnu rẹ, nígbà tí o bá sì ranti rẹ̀, yóo dàbí ìkún omi tí ó ti wọ́ lọ. Ayé rẹ yóo mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan lọ; òkùnkùn rẹ yóo sì dàbí òwúrọ̀. Ọkàn rẹ óo balẹ̀, nítorí pé o ní ìrètí, a óo dáàbò bò ọ́, o óo sì sinmi láìséwu. O óo sùn, láìsí ìdágìrì, ọpọlọpọ eniyan ni wọn óo sì máa wá ojurere rẹ. Àwọn ẹni ibi óo pòfo; gbogbo ọ̀nà tí wọ́n lè gbà sá àsálà ni yóo parẹ́ mọ́ wọn lójú, ikú ni yóo sì jẹ́ ìrètí wọn.” Jobu dáhùn pé: “Láìsí àní àní, ẹ̀yin ni agbẹnusọ gbogbo eniyan, bí ẹ bá jáde láyé, ọgbọ́n kan kò tún ní sí láyé mọ́. Bí ẹ ti ní ìmọ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi náà ní, ẹ kò sàn jù mí lọ. Ta ni kò mọ irú nǹkan, tí ẹ̀ ń sọ yìí? Mo wá di ẹlẹ́yà lójú àwọn ọ̀rẹ́ mi, èmi tí mò ń ké pe Ọlọrun, tí ó sì ń dá mi lóhùn; èmi tí mo jẹ́ olódodo ati aláìlẹ́bi, mo wá di ẹlẹ́yà. Lójú ẹni tí ara tù, ìṣòro kì í báni láìnídìí. Lójú rẹ̀, ẹni tí ó bá ṣìṣe ni ìṣòro wà fún. Àwọn olè ń gbé ilé wọn ní alaafia, àwọn tí wọn ń mú Ọlọrun bínú wà ní àìléwu, àwọn tí ó jẹ́ pé agbára wọn ni Ọlọrun wọn. “Ṣugbọn, bèèrè lọ́wọ́ àwọn ẹranko, wọn óo sì kọ́ ọ, bi àwọn ẹyẹ, wọn yóo sì sọ fún ọ; tabi kí o bi àwọn koríko, wọn yóo sì kọ́ ọ, àwọn ẹja inú òkun yóo sì ṣe àlàyé fún ọ. Ta ni kò mọ̀ ninu gbogbo wọn pé OLUWA ló ṣe èyí? Ọwọ́ rẹ̀ ni ìyè gbogbo ẹ̀dá wà, ati ẹ̀mí gbogbo eniyan. Ṣebí etí a máa dán ọ̀rọ̀ wò, ahọ́n a sì máa tọ́ oúnjẹ wò? “Àgbà ló ni ọgbọ́n, àwọn ogbó tí wọ́n ti pẹ́ láyé ni wọ́n ni òye. Ọlọrun ló ni ọgbọ́n ati agbára, tirẹ̀ ni ìmọ̀ràn ati ìmọ̀. Ohun tí Ọlọrun bá wó lulẹ̀, ta ló lè tún un kọ́? Tí ó bá ti eniyan mọ́lé, ta ló lè tú u sílẹ̀? Bí ó bá dáwọ́ òjò dúró, ọ̀gbẹlẹ̀ a dé, bí ó bá sí rọ òjò, omi a bo ilẹ̀. Òun ló ni agbára ati ọgbọ́n, òun ló ni ẹni tí ń tan ni jẹ, òun náà ló ni ẹni tí à ń tàn. Ó pa ọgbọ́n mọ́ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ninu, ó sì sọ àwọn onídàájọ́ di òmùgọ̀. Ó tú àwọn tí àwọn ọba dè mọ́lẹ̀, ó sì so ẹ̀wọ̀n mọ́ àwọn ọba gan-an nídìí. Ó rẹ àwọn alufaa sílẹ̀, ó sì gba agbára lọ́wọ́ àwọn alágbára. Ó pa àwọn agbẹnusọ lẹ́nu mọ́, ó gba ìmọ̀ àwọn àgbààgbà. Ó dójúti àwọn olóyè, ó tú àmùrè àwọn alágbára. Ó mú ohun òkùnkùn wá sí ìmọ́lẹ̀, ó sì tan ìmọ́lẹ̀ sí òkùnkùn biribiri. Òun níí sọ àwọn orílẹ̀-èdè di ńlá, òun náà níí sìí tún pa wọ́n run: Òun níí kó àwọn orílẹ̀-èdè jọ, òun náà níí sì ń tú wọn ká. Ó gba ìmọ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn ìjòyè ní gbogbo ayé, ó sì sọ wọ́n di alárìnká ninu aṣálẹ̀, níbi tí ọ̀nà kò sí. Wọ́n ń táràrà ninu òkùnkùn, ó sì mú kí wọ́n máa ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n bí ọ̀mùtí. “Gbogbo ìwọ̀nyí ni ojú mi ti rí rí, tí etí mi ti gbọ́, tí ó sì yé mi. Ohun tí ẹ mọ̀ wọnyi, èmi náà mọ̀ ọ́n, ẹ kò sàn jù mí lọ. Ṣugbọn n óo bá Olodumare sọ̀rọ̀, Ọlọrun ni mo sì fẹ́ bá rojọ́. Ẹ̀yin òpùrọ́ ati ẹlẹ́tàn wọnyi, ẹ̀yin oníṣègùn tí ẹ kò lè wonisàn. Ẹ̀ bá jẹ́ pa ẹnu yín mọ́ ni, à bá pè yín ní ọlọ́gbọ́n! Nisinsinyii ẹ gbọ́ èrò ọkàn mi, kí ẹ sì fetísí àròyé mi. Ṣé ẹ óo máa parọ́ ní orúkọ Ọlọrun ni, kí ẹ sì máa sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ní orúkọ rẹ̀? Ṣé ẹ fẹ́ máa ṣe ojuṣaaju fún Ọlọrun ni? Tabi ẹ fẹ́ jẹ́ agbẹjọ́rò rẹ̀? Ṣé ẹ óo yege bí ó bá dán yín wò? Tabi ẹ lè tan Ọlọrun bí ẹni tan eniyan? Dájúdájú, yóo ba yín wí, bí ẹ bá ń ṣe ojuṣaaju níkọ̀kọ̀. Ògo rẹ̀ yóo dẹ́rùbà yín, jìnnìjìnnì rẹ̀ yóo dà bò yín. Àwọn òwe yín kò wúlò, àwíjàre yín kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Ẹ dákẹ́, kí n ráyè sọ tèmi, kí ohun tí yóo bá dé bá mi dé bá mi. N óo dijú, n óo fi ẹ̀mí ara mi wéwu. Wò ó, yóo pa mí; n kò ní ìrètí; sibẹ n óo wí àwíjàre tèmi níwájú rẹ̀. Èyí ni yóo jẹ́ ìgbàlà mi, nítorí pé ẹni tí kò mọ Ọlọrun, kò ní lè dúró níwájú rẹ̀. Fetí sílẹ̀ dáradára sí ọ̀rọ̀ mi, kí o sì gbọ́ mi ní àgbọ́yé. Wò ó, mo ti múra ẹjọ́ mi sílẹ̀; mo sì mọ̀ pé n óo gba ìdáláre. Ta ni yóo wá bá mi rojọ́? Bí ó bá wá, n óo dákẹ́, n óo sì kú. Nǹkan meji péré ni mo fẹ́ kí o ṣe fún mi, n kò sì ní farapamọ́ fún ọ: ká ọwọ́ ibinu rẹ kúrò lára mi, má sì ṣe jẹ́ kí jìnnìjìnnì rẹ dà bò mí. Lẹ́yìn náà, sọ̀rọ̀, n óo sì fèsì; tabi kí o jẹ́ kí èmi sọ̀rọ̀, kí o sì fún mi lésì. Báwo ni àìdára ati ẹ̀ṣẹ̀ mi ti pọ̀ tó? Jẹ́ kí n mọ ẹ̀ṣẹ̀ mi, ati ibi tí mo ti kọjá ààyè mi. Kí ló dé tí o fi fi ara pamọ́ fún mi tí o kà mí kún ọ̀tá rẹ? Ṣé o óo máa dẹ́rùba ewé lásán tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kiri, tabi o óo máa lépa ìyàngbò gbígbẹ? O ti kọ àkọsílẹ̀ burúkú nípa mi, o mú mi jìyà ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mi. O kó ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ sí mi lẹ́sẹ̀, ò ń ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ mi, o sì pa ààlà tí n kò gbọdọ̀ rékọjá. Eniyan ń ṣègbé lọ bí ohun tí ó ń jẹrà, bí aṣọ tí ikán ti mu. “Ẹnikẹ́ni tí obinrin bá bí, ọlọ́jọ́ kúkúrú ni, ó sì kún fún ìpọ́njú. Yóo kọ́ yọ bí òdòdó, lẹ́yìn náà yóo sì rẹ̀ dànù. Yóo kọjá lọ bí òjìji, kò sì ní sí mọ́. Ṣé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni o dojú kọ, tí ò ń bá ṣe ẹjọ́? Ta ló lè mú ohun mímọ́ jáde láti inú ohun tí kò mọ́? Kò sí ẹni náà. Níwọ̀n ìgbà tí a ti dá ọjọ́ fún un, tí o mọ iye oṣù rẹ̀, tí o sì ti pa ààlà tí kò lè rékọjá. Mú ojú rẹ kúrò lára rẹ̀, kí ó lè sinmi, kí ó sì lè gbádùn ọjọ́ ayé rẹ̀ bí alágbàṣe. “Nítorí pé ìrètí ń bẹ fún igi tí wọn gé, yóo tún pada rúwé, ẹ̀ka rẹ̀ kò sì ní ṣe aláìsọ. Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ògbólógbòó ninu ilẹ̀, tí kùkùté rẹ̀ sì kú, bí ó bá ti gbóòórùn omi, yóo sọ, yóo sì yọ ẹ̀ka bí ọ̀dọ́ irúgbìn. Ṣugbọn bí eniyan bá kú, a óo tẹ́ ẹ sinu ibojì, bí ó bá ti gbẹ́mìí mì, ó di aláìsí. Bí adágún omi tíí gbẹ, ati bí odò tíí ṣàn lọ, tí sìí gbẹ, bẹ́ẹ̀ ni eniyan ṣe é sùn, tí kì í sìí jí mọ́, títí tí ọ̀run yóo fi kọjá lọ, kò ní jí, tabi kí ó tilẹ̀ rúnra láti ojú oorun. Ìbá sàn kí o fi mí pamọ́ sinu ibojì, kí o pa mí mọ́ títí inú rẹ yóo fi rọ̀, ò bá dá àkókò fún mi, kí o sì ranti mi. Bí eniyan bá kú, ǹjẹ́ yóo tún jí mọ́? N óo dúró ní gbogbo ọjọ́ làálàá mi, n óo máa retí, títí ọjọ́ ìdáǹdè mi yóo fi dé. O óo pè mí, n ó sì dá ọ lóhùn, o óo máa ṣe àfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Nígbà náà, o óo máa tọ́ ìṣísẹ̀ mi, o kò sì ní ṣọ́ àwọn àṣìṣe mi. O óo di àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi sinu àpò, o óo sì bo àwọn àìdára mi mọ́lẹ̀. “Ṣugbọn òkè ńlá ṣubú, ó sì rún wómúwómú, a sì ṣí àpáta nídìí kúrò ní ipò rẹ̀. Bí omi ṣe é yìnrìn òkúta, tí àgbàrá sì í wọ́ erùpẹ̀ ilẹ̀ lọ, bẹ́ẹ̀ ni o óo ṣe sọ ìrètí eniyan di òfo. O ṣẹgun rẹ̀ títí lae, ó sì kọjá lọ, o yí àwọ̀ rẹ̀ pada, o sì mú kí ó lọ. Wọ́n dá àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́lá, ṣugbọn kò mọ̀, a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, sibẹ kò rí i. Ìrora ara rẹ̀ nìkan ló mọ̀, ọ̀fọ̀ ara rẹ̀ nìkan ni ó ń ṣe.” Elifasi ará Temani bá dáhùn pé, “Ṣé ọlọ́gbọ́n a máa fọ èsì tí kò mọ́gbọ́n lọ́wọ́? Kí ó dàbí àgbá òfìfo? Kí ó máa jiyàn lórí ọ̀rọ̀ tí kò wúlò, tabi ọ̀rọ̀ tí kò níláárí? Ṣugbọn ò ń kọ ìbẹ̀rù Ọlọrun sílẹ̀, o sì ń dènà adura níwájú rẹ̀. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ni ó ń fa irú ọ̀rọ̀ tí ń ti ẹnu rẹ jáde, ètè rẹ sì kún fún àrékérekè. Ẹnu rẹ ni ó dá ọ lẹ́bi, kì í ṣe èmi; ẹ̀rí tí ò ń jẹ́ nípa rẹ ní ń ta kò ọ́. “Ṣé ìwọ ni ẹni kinni tí wọ́n kọ́ bí láyé? Tabi o ṣàgbà àwọn òkè? Ṣé o wà ninu ìgbìmọ̀ Ọlọrun? Tabi ìwọ nìkan ni o rò pé o gbọ́n? Kí ni o mọ̀, tí àwa náà kò mọ̀? Òye kí ni o ní, tí ó jẹ́ ohun ìpamọ́ fún àwa? Àwọn tí wọ́n hu ewú lórí wà láàrin wa, ati àwọn àgbàlagbà, àwọn tí wọ́n dàgbà ju baba rẹ lọ. Ṣé ìtùnú Ọlọrun kò tó fún ọ ni, àní ọ̀rọ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ tí ó ń sọ fún ọ? Àgbéré kí lò ń ṣe, tí o sì ń fi ojú burúkú wò wá. Tí ọkàn rẹ yipada kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun, tí ò ń jẹ́ kí irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ti ẹnu rẹ jáde? Kí ni eniyan jẹ́, tí ó fi lè mọ́ níwájú Ọlọrun? Kí ni ẹnikẹ́ni tí obinrin bí já mọ́, tí ó fi lè jẹ́ olódodo? Wò ó, Ọlọrun kò fọkàn tán àwọn angẹli, àwọn ọ̀run kò sì mọ́ níwájú rẹ̀. Kí á má tilẹ̀ wá sọ ti eniyan tí ó jẹ́ aláìmọ́ ati ẹlẹ́gbin, tí ń mu ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹni mu omi! “Fetí sílẹ̀, n óo sọ fún ọ, n óo sọ ohun tí ojú mi rí, (ohun tí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n sọ, tí àwọn baba wọn kò sì fi pamọ́, àwọn nìkan ni a fún ní ilẹ̀ náà, àlejò kankan kò sì sí láàrin wọn). Ẹni ibi ń yí ninu ìrora ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, àní, ní gbogbo ọdún tí a là sílẹ̀ fún ìkà. Etí rẹ̀ kún fún igbe tí ó bani lẹ́rù, ninu ìdẹ̀ra rẹ̀ àwọn apanirun yóo dìde sí i. Kò gbàgbọ́ pé òun lè jáde kúrò ninu òkùnkùn; ati pé dájú, ikú idà ni yóo pa òun. Ó ń wá oúnjẹ káàkiri, ó ń bèèrè pé, ‘Níbo ló wà?’ Òun gan-an sì nìyí, oúnjẹ àwọn igún! Ó mọ̀ pé ọjọ́ òkùnkùn ti súnmọ́ tòsí. Ìdààmú ati ìrora dẹ́rùbà á, wọ́n ṣẹgun rẹ̀, bí ọba tí ó múra ogun. Nítorí pé ó ṣíwọ́ sókè sí Ọlọrun, o sì ṣe oríkunkun sí Olodumare, ó ń ṣe oríkunkun sí i, ó sì gbé apata tí ó nípọn lọ́wọ́ láti bá a jà; nítorí pé ó sanra tóbẹ́ẹ̀ tí ojú rẹ̀ yíbò, ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ sì jẹ́ kìkì ọ̀rá. Ó ń gbé ìlú tí ó ti di ahoro, ninu àwọn ilé tí eniyan kò gbọdọ̀ gbé, àwọn ilé tí yóo pada di òkítì àlàpà. Kò ní ní ọrọ̀, ohun tí ó bá ní, kò ní pẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, òun alára kò sì ní fìdí múlẹ̀. Kò ní bọ́ kúrò ninu òkùnkùn, iná yóo jó àwọn ẹ̀ka rẹ̀, afẹ́fẹ́ yóo sì fẹ́ àwọn ìtànná rẹ̀ dànù. Kí ó má gbẹ́kẹ̀lé òfo, kí ó má máa tan ara rẹ̀ jẹ, nítorí òfo ni yóo jẹ́ èrè rẹ̀. A ó san án fún un lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ lọ́jọ́ àìpé, gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ ni yóo sì gbẹ. Yóo gbọn àwọn èso rẹ̀ tí kò tíì pọ́n dànù, bí àjàrà, yóo sì gbọn àwọn ìtànná rẹ̀ dànù, bí igi olifi. Nítorí asán ni àwùjọ àwọn tí wọn kò mọ Ọlọ́run, iná yóo sì jó ilé àwọn tí ń gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀. Wọ́n ń ro èrò ìkà, wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ibi, wọ́n sì ń pète ẹ̀tàn lọ́kàn.” Jobu bá dáhùn pé, “Èmi náà ti gbọ́ irú nǹkan wọnyi rí, ọlọ́rọ̀ ìtùnú kòbákùngbé ni gbogbo yín. Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ asán tí ẹ̀ ń sọ yìí tilẹ̀ lópin? Àbí, kí ní ń fa gbogbo àríyànjiyàn yìí? Bí ẹ bá wà ní ipò mi, èmi náà lè sọ̀rọ̀ bí ẹ tí ń sọ̀rọ̀ yìí, kí n da ọ̀rọ̀ bò yín, kí n sì máa mi orí si yín. Mo lè fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi fun yín lókun, kí ọ̀rọ̀ ìtùnú mi sì mú kí ara tù yín. “Bí mo sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ kò mú kí ara tù mí, bí mo bá sì dákẹ́, ṣé dídákẹ́ lè tán ìrora mi? Dájúdájú Ọlọrun ti dá mi lágara, ó ti sọ gbogbo ilé mi di ahoro. Híhunjọ tí ara mi hunjọ, jẹ́ ẹ̀rí láti ta kò mí; rírù tí mo rù ta àbùkù mi, ó sì hàn lójú mi. Ó ti fi ibinu fà mí ya, ó sì kórìíra mi; ó pa eyín keke sí mi; ọ̀tá mi sì ń fojú burúkú wò mí. Àwọn eniyan ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n ń gbá mi létí, wọ́n kó ara wọn jọ sí mi. Ọlọrun fà mí lé eniyan burúkú lọ́wọ́, ó mú kí n ṣubú sí ọwọ́ àwọn ìkà. Nígbà tí ó dára fún mi, ó fi ẹ̀yìn mi wọ́nlẹ̀, ó fún mi lọ́rùn, ó gbé mi ṣánlẹ̀, ó sì gbọ̀n mí yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́; ó yàn mí sọjú bí àmì ìtafà sí. Àwọn tafàtafà rẹ̀ yí mi ká, ó la kíndìnrín mi láìṣàánú mi, ó sì tú òróòro mi jáde. Ó ń gbógun tì mí nígbà gbogbo, ó pakuuru sí mi bí ọmọ ogun. “Mo fi aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara, mo sùn gbalaja sinu erùpẹ̀. Mo sọkún títí ojú mi fi pọ́n, omijé sì mú kí ojú mi ṣókùnkùn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò ṣe ibi, adura mi sì mọ́. “Ìwọ ilẹ̀, má ṣe bo ẹ̀jẹ̀ mi mọ́lẹ̀, má sì jẹ́ kí igbe mi já sí òfo. Nisinsinyii, ẹlẹ́rìí mi ń bẹ lọ́run, alágbàwí mi sì ń bẹ lókè. Àwọn ọ̀rẹ́ mi ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà, mo sì ń sọkún sí Ọlọrun, ìbá ṣe pé ẹnìkan lè ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì lọ́dọ̀ Ọlọrun, bí eniyan ti lè ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì rẹ̀ níwájú eniyan. Lẹ́yìn ọdún díẹ̀ sí i, n óo lọ àjò àrèmabọ̀. “Ọkàn mi bàjẹ́, ọjọ́ ayé mi ti dópin, ibojì sì ń dúró dè mí. Dájúdájú àwọn ẹlẹ́yà yí mi káàkiri, wọ́n ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ lojukooju. Fi nǹkan ẹ̀jẹ́ kan lélẹ̀ fún mi lọ́dọ̀ rẹ; ta ló wà níbẹ̀ tí yóo ṣe onídùúró fún mi? Níwọ̀n ìgbà tí o ti mú ọkàn wọn yigbì sí ìmọ̀, nítorí náà, o kò ní jẹ́ kí wọ́n borí. Bí ẹnìkan bá hùwà ọ̀dàlẹ̀, tí ó ṣòfófó àwọn ọ̀rẹ́, kí ó lè pín ninu ohun ìní wọn, àwọn ọmọ olúwarẹ̀ yóo jìyà. O ti sọ mí di ẹni àmúpòwe láàrin àwọn eniyan, mo di ẹni tí à ń tutọ́ sí lára. Ìbànújẹ́ sọ ojú mi di bàìbàì, gbogbo ẹ̀yà ara mi dàbí òjìji. Èyí ya àwọn olódodo lẹ́nu, aláìlẹ́bi sì dojú kọ ẹni tí kò mọ Ọlọrun. Sibẹsibẹ olódodo kò fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀, ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ mọ́ sì ń lágbára sí i. Ṣugbọn ní tiyín, bí ẹ tilẹ̀ ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ, n kò ní ka ẹnikẹ́ni kún ọlọ́gbọ́n láàrin yín. “Ọjọ́ ayé mi ti dópin, èrò ọkàn mi ti dàrú, àwọn ohun tí ọkàn mi ń fẹ́ sì ti di asán. Wọ́n sọ òru di ọ̀sán, wọ́n ń sọ pé, ‘Ìmọ́lẹ̀ kò jìnnà sí òkùnkùn.’ Bí mo bá ní ìrètí pé ibojì yóo jẹ́ ilé mi, tí mo tẹ́ ibùsùn mi sinu òkùnkùn, bí mo bá pe isà òkú ní baba, tí mo sì pe ìdin ní ìyá tabi arabinrin mi, níbo ni ìrètí mi wá wà? Ta ló lè rí ìrètí mi? Ṣé yóo lọ sí ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ ni? Ṣé àwa mejeeji ni yóo jọ wọ inú erùpẹ̀ lọ?” Bilidadi ará Ṣuha bá tún dáhùn pé, “Ìgbàwo ni o óo sinmi ẹjọ́ tí ò ń tò yìí? Ohun tí a tí ń bá ọ sọ ni kí o gbé yẹ̀wò, kí á lè sọ èyí tí a tún fẹ́ sọ. Kí ló dé tí o fi kà wá sí ẹranko, tí a di òmùgọ̀ lójú rẹ? Ìwọ tí o faraya nítorí inú ń bí ọ, ṣé kí á sá kúrò láyé nítorí rẹ ni, tabi kí á ṣí àwọn àpáta nípò pada? “Nítòótọ́, a ti pa fìtílà ẹni ibi, ahọ́n iná rẹ̀ kò sì mọ́lẹ̀ mọ́. Inú àgọ́ rẹ̀ ṣókùnkùn, a sì ti pa àtùpà ìgbèrí rẹ̀. Agbára rẹ̀ ti dín kù, ète rẹ̀ sì gbé e ṣubú. Ó ti ẹsẹ̀ ara rẹ̀ bọ àwọ̀n, ó ń rìn lórí ọ̀fìn. Tàkúté ti mú un ní gìgísẹ̀, ó ti kó sinu pańpẹ́. A dẹ okùn sílẹ̀ fún un, a sì dẹ pańpẹ́ sí ojú ọ̀nà rẹ̀. “Ìbẹ̀rù yí i ká, wọ́n ń lé e kiri. Ebi pa agbára mọ́ ọn ninu, ìṣòro sì ti ṣetán láti gbé e ṣubú. Àìsàn burúkú jẹ awọ ara rẹ̀, àkọ́bí ikú jẹ ẹ́ tọwọ́ tẹsẹ̀. A fipá wọ́ ọ kúrò ninu àgọ́ rẹ̀ tí ó gbẹ́kẹ̀lé, a sì mú un lọ sọ́dọ̀ Ọba Ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀. Àgọ́ rẹ̀ kún fún àwọn tí kì í ṣe tirẹ̀, imí-ọjọ́ fọ́nká sí gbogbo ibùgbé rẹ̀. Gbòǹgbò rẹ̀ gbẹ nísàlẹ̀, ẹ̀ka rẹ̀ sì gbẹ lókè. Ó di ẹni ìgbàgbé lórílẹ̀ ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò gbórúkọ rẹ̀ mọ́ ní ìgboro. Wọ́n tì í láti inú ìmọ́lẹ̀ sinu òkùnkùn, wọ́n lé e kúrò láyé. Kò lọ́mọ, kò lọ́mọ ọmọ, kò sì sí ẹni tí yóo rọ́pò rẹ̀ ní ibùgbé rẹ̀, láàrin àwọn eniyan rẹ̀. Ẹnu yóo ya àwọn ará ìwọ̀ oòrùn, ìwárìrì yóo sì mú àwọn ará ìlà oòrùn, nítorí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí i. Dájúdájú bẹ́ẹ̀ ni ibùgbé ẹni ibi yóo rí, àní, ilé ẹni tí kò mọ Ọlọrun.” Jobu bá dáhùn, ó ní, “Ẹ óo ti ni mí lára pẹ́ tó, tí ẹ óo máa fi ọ̀rọ̀ yín bà mí ninu jẹ́? Ẹ kẹ́gàn mi ní àìníye ìgbà ojú kò tilẹ̀ tì yín láti ṣẹ̀ mí? Bí ó bá tilẹ̀ jẹ́ pé lótìítọ́ ni mo ṣẹ̀, ṣebí ara mi ni àṣìṣe mi wà? Bí ẹ bá rò pé ẹ sàn jù mí lọ, tí ẹ sì rò pé ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ mi ni ìdààmú mi, ẹ mọ̀ dájú pé Ọlọrun ni ó dá mi lẹ́bi, tí ó sì fi àwọ̀n rẹ̀ yí mi ká. Mò ń kérora pé wọ́n dá mi lóró, ṣugbọn kò sí ẹni tí ó dá mi lóhùn; mo pariwo, pariwo, ṣugbọn kò sí ẹni tí ó dìde láti ṣe ẹ̀tọ́. Ọlọrun ti dí ọ̀nà mọ́ mi, kí n má baà kọjá, ó mú ọ̀nà mi ṣókùnkùn. Ó bọ́ ògo mi kúrò, ó sì gba adé orí mi. Ó ba ayé mi jẹ́ ní gbogbo ọ̀nà, ó sì ti parí fún mi, ó fa ìrètí mi tu bí ẹni fa igi tu. Ibinu rẹ̀ ń jó mi bí iná, ó kà mí kún ọ̀tá rẹ̀. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kó ara wọn jọ, wọ́n dó tì mí, wọ́n sì pa àgọ́ tiwọn yí àgọ́ mi ká. “Ó mú kí àwọn arakunrin mi jìnnà sí mi, àwọn ojúlùmọ̀ mi sì di àjèjì sí mi. Àwọn ìyekan mi ati àwọn ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ ti já mi kulẹ̀. Àwọn àlejò tí wọ́n wọ̀ sí ilé mi ti gbàgbé mi. Àwọn iranṣẹbinrin mi kà mí kún àlejò, wọ́n ń wò mí bí àjèjì. Mo pe iranṣẹ mi, ṣugbọn kò dáhùn, bíbẹ̀ ni mo níláti máa bẹ̀ ẹ́. Mo di ẹni ìríra lọ́dọ̀ iyawo mi, mo sì ń rùn sí àwọn ọmọ ìyá mi. Àwọn ọmọde pàápàá ń fojú tẹmbẹlu mi; bí mo bá dìde wọn á máa sọ̀rọ̀ sí mi. Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ ti rí mi sá, àwọn tí mo nífẹ̀ẹ́ ti kẹ̀yìn sí mi. Mo rù kan egungun, agbára káká ni mo fi sá àsálà. Ẹ ṣàánú mi, ẹ ṣàánú mi, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, nítorí ọwọ́ Ọlọrun ti bà mí! Ọlọrun ń lépa mi, ẹ̀yin náà sì tún ń lépa mi! Kí ló dé tí ẹran ara mi kò to yín? “À bá lè kọ ọ̀rọ̀ mi sílẹ̀! Àní, kí á kọ ọ́ sinu ìwé! Kí á fi kálàmú irin ati òjé kọ ọ́ sórí àpáta, kí ó wà níbẹ̀ títí lae. Ṣugbọn mo mọ̀ pé Olùdáǹdè mi ń bẹ láàyè, ati pé, níkẹyìn, yóo dìde dúró lórí ilẹ̀ yóo sì jẹ́rìí mi, lẹ́yìn tí awọ ara mi bá ti díbàjẹ́, ṣugbọn ninu ara mi ni n óo rí Ọlọ́run. Fúnra mi ni n óo rí i, ojú ara mi ni n óo sì fi rí i, kì í ṣe ti ẹlòmíràn. “Ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì ninu mi! Bí ẹ bá wí pé, ‘Báwo ni a óo ṣe lépa rẹ̀!’ Nítorí pé òun ló jẹ̀bi ọ̀rọ̀ yìí, ṣugbọn, ẹ bẹ̀rù idà, nítorí pé ìrúnú níí fa kí á fi idà pa eniyan, kí ẹ lè mọ̀ dájú pé ìdájọ́ ń bẹ.” Sofari, ará Naama bá dáhùn pé, “Lọ́kàn mi, mo fẹ́ fèsì sí ọ̀rọ̀ rẹ, ara sì ń wá mi, bí ẹni pé kí n dá ọ lóhùn. Mo gbọ́ èébú tí o bú mi, mo sì mọ irú èsì tí ó yẹ kí n fọ̀. Ṣé o kò mọ̀ bẹ́ẹ̀ láti ìgbà àtijọ́, láti ìgbà tí wọ́n ti dá eniyan sórí ilẹ̀ ayé, pé bí inú eniyan burúkú bá ń dùn, tí ẹni tí kò mọ Ọlọrun bá ń yọ̀, fún ìgbà díẹ̀ ni. Bí ìgbéraga rẹ̀ tilẹ̀ ga, tí ó kan ọ̀run, tí orí rẹ̀ kan sánmà, yóo ṣòfò títí lae bí ìgbọ̀nsẹ̀ ara rẹ̀, àwọn tí wọ́n mọ̀ ọ́n yóo bèèrè pé, ‘Níbo ló wà?’ Yóo parẹ́ bí àlá, yóo sì di àwátì, yóo pòórá bí ìran tí a rí lóru. Ojú tí ó ti ń rí i tẹ́lẹ̀ kò ní rí i mọ́, ààyè rẹ̀ yóo sì ṣófo. Àwọn ọmọ rẹ̀ yóo máa wá ojurere àwọn aláìní, wọn yóo sì san ohun tí baba wọn gbà lọ́wọ́ aláìní pada. Bí ó tilẹ̀ dàbí ọ̀dọ́, tí ó lágbára, sibẹ yóo lọ sí ibojì, yóo sì di erùpẹ̀. Bí ọ̀rọ̀ ìkà tilẹ̀ dùn ní ẹnu rẹ̀, tí ó sì fi pamọ́ sí abẹ́ ahọ́n rẹ̀, bí ó tilẹ̀ lọ́ra láti sọ ọ́ jáde, tí ó pa ẹnu mọ́, sibẹsibẹ oúnjẹ rẹ̀ a máa dà á ninu rú, ó sì ti dàbí oró ejò paramọ́lẹ̀ ninu rẹ̀. Gbogbo owó tí ó kó jẹ ni ó tún ń pọ̀ jáde; Ọlọrun ní ń pọ̀ wọ́n jáde ninu ikùn rẹ̀. Yóo mu oró ejò, ahọ́n paramọ́lẹ̀ yóo pa á. Kò ní gbádùn oyin ati wàrà tí ń ṣàn bí odò. Kò ní jẹ èrè wahala rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní gbádùn èrè tí ó bá jẹ nídìí òwò rẹ̀. Nítorí pé ó ti tẹ aláìní mọ́lẹ̀, ó sì ti pa wọ́n tì sí apákan ó sì fi ipá gba ilé tí kò kọ́. Nítorí pé oníwọ̀ra ni, tí ọkàn rẹ̀ bá nàró sí nǹkankan, kò lè pa á mọ́ra. Kì í jẹ àjẹṣẹ́kù, nítorí náà, ọlá rẹ̀ kò le tọ́jọ́. Ninu ọlá ńlá rẹ̀ yóo wà ninu àhámọ́, ìbànújẹ́ yóo máa fi tagbára-tagbára bá a jà. Dípò kí ó jẹun ní àjẹyó, ibinu ńlá ni Ọlọrun yóo rán sí i, tí yóo sì dà lé e lórí. Bí ó bá ti ń sá fún idà, bẹ́ẹ̀ ni ọfà bàbà yóo gún un ní àgúnyọ-lódì-keji. Bí ó bá fa ọfà jáde kúrò lára rẹ̀, tí ṣóńṣó orí ọfà jáde láti inú òróòro rẹ̀, ìbẹ̀rùbojo yóo dé bá a. Òkùnkùn biribiri ń dúró dè é, iná tí eniyan kò dá ni yóo jó o ní àjórun, ohun ìní tí ó kù ní ibùgbé rẹ̀ yóo sì parun. Ọ̀run yóo fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ hàn, ilẹ̀ yóo dojú ìjà kọ ọ́. Ibinu Ọlọrun gba àwọn ohun ìní rẹ̀ lọ, àgbàrá ibinu yóo gbá wọn dànù. Bẹ́ẹ̀ ni ìpín ẹni ibi yóo rí. Ọlọrun ni ó ti yàn án bẹ́ẹ̀ láti ilẹ̀ wá.” Jobu dáhùn pé, “Ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi dáradára, kí ẹ sì jẹ́ kí ó jẹ́ ìtùnú fun yín. Ẹ farabalẹ̀, kí ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, lẹ́yìn náà, ẹ lè máa fi mí ṣẹ̀sín ǹṣó. Ṣé eniyan ni mò ń bá rojọ́ ni? Kí ló dé tí n óo fi mú sùúrù? Ẹ wò mí, kí ẹnu yà yín, kí ẹ sì fọwọ́ bo ẹnu. Nígbà tí mo ro ohun tí ó dé bá mi, ẹ̀rù bà mí, mo sì wárìrì. Kí ló dé tí eniyan burúkú fi wà láàyè, tí ó di arúgbó, tí ó sì di alágbára? Àwọn ọmọ wọn ati arọmọdọmọ wọn di eniyan pataki pataki lójú ayé wọn. Kò sí ìfòyà ninu ilé wọn, bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun kò jẹ wọ́n níyà. Àwọn mààlúù wọn ń gùn, wọ́n sì ń bímọ ní àbíyè. Wọn a máa kó àwọn ọmọ wọn jáde bí agbo ẹran, àwọn ọmọ wọn a sì máa ṣe àríyá. Wọn a máa fi aro, ìlù, ati fèrè kọrin, wọn a sì máa yọ̀ sí ohùn dùùrù. Wọn a máa gbé inú ọlá, wọn a sì máa kú ikú alaafia. Wọ́n ń sọ fún Ọlọrun pé, ‘Fi wá sílẹ̀! A kò fẹ́ mọ òfin rẹ. Ta ni Olodumare, tí a óo fi máa sìn ín? Èrè wo ni ó wà níbẹ̀ fún wa bí à ń gbadura sí i?’ Wọ́n rò pé ìkáwọ́ wọn ni ọlà wọn wà, nítèmi n kò lè tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn eniyan burúkú. “Ìgbà mélòó ni à ń pa fìtílà ẹni ibi? Ìgbà mélòó ni iṣẹ́ ibi wọn ń dà lé wọn lórí? Tabi tí Ọlọrun ṣe ìpín wọn ní ìrora ninu ibinu rẹ̀? Ìgbà mélòó ni wọ́n dàbí àgékù koríko, tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kiri, tabi bí ìyàngbò tí ìjì ń gbé lọ? “O ní, ‘Ọlọrun ń to àìdára wọn jọ de àwọn ọmọ wọn.’ Jẹ́ kí ó dà á lé wọn lórí, kí wọ́n baà lè mọ ohun tí wọ́n ṣe. Jẹ́ kí wọ́n fi ojú ara wọn rí ìparun ara wọn, kí wọ́n sì rí ibinu Olodumare. Kí ni ó kàn wọ́n pẹlu ilé wọn mọ́, lẹ́yìn tí wọn bá ti kú, nígbà tí a bá ti ké ọjọ́ wọn kúrò lórí ilẹ̀. Ṣé ẹnìkan lè kọ́ Ọlọrun ní ìmọ̀, nígbà tí ó jẹ́ pé òun ni onídàájọ́ àwọn tí wọ́n wà ní ibi gíga? Ẹnìkan kú ninu ọpọlọpọ ọrọ̀, nítorí pé ó wà ninu ìdẹ̀ra ati àìfòyà, ara rẹ̀ ń dán fún sísanra, ara sì tù ú dé mùdùnmúdùn. Ẹlòmíràn kú pẹlu ìbànújẹ́ ọkàn, láìtọ́ ohun rere kankan wò rí. Bákan náà ni gbogbo wọn ṣe sùn ninu erùpẹ̀, tí ìdin sì bò wọ́n. “Wò ó! Mo mọ èrò ọkàn yín, mo sì mọ ète tí ẹ ní sí mi láti ṣe mí níbi. Nítorí ẹ wí pé, ‘Níbo ni ilé àwọn eniyan ńlá wà; níbo sì ni àgọ́ àwọn aṣebi wà?’ Ṣé ẹ kò tíì bèèrè ọ̀nà lọ́wọ́ àwọn arìnrìnàjò? Ṣé ẹ kò sì tíì gba ẹ̀rí wọn, pé, a dá ẹni ibi sí ní ọjọ́ ìdàrúdàpọ̀, ati pé a gbà á là ní ọjọ́ ibinu? Kò sẹ́ni tó jẹ́ fẹ̀sùn kan ẹni ibi lójú rẹ̀, tabi kí ó gbẹ̀san nǹkan burúkú tí ó ṣe. Nígbà tí a bá gbé e lọ sí itẹ́, àwọn olùṣọ́ a máa ṣọ́ ibojì rẹ̀. Ẹgbẹẹgbẹrun èrò a tẹ̀lé e lọ sí ibojì, àìmọye eniyan a sì sin òkú rẹ̀; kódà, ilẹ̀ á dẹ̀ fún un ní ibojì rẹ̀. Nítorí náà, kí ni ìsọkúsọ tí ẹ lè fi tù mí ninu? Kò sóhun tó kù ninu ọ̀rọ̀ yín, tó ju irọ́ lọ.” Elifasi ará Temani bá dáhùn pé, “Ǹjẹ́ eniyan lè wúlò fún Ọlọrun? Nítòótọ́, bí eniyan tilẹ̀ jẹ́ ọlọ́gbọ́n, ara rẹ̀ ni ó wúlò fún. Ǹjẹ́ jíjẹ́ olódodo rẹ̀ ṣe ohun rere kan fún Olodumare, tabi kí ni èrè rẹ̀ bí ó bá jẹ́ ẹni pípé? Ṣé nítorí pé o bẹ̀rù rẹ̀ ni ó ṣe bá ọ wí, tí ó sì ń dá ọ lẹ́jọ́? Ṣebí ìwà ibi rẹ ló pọ̀; tí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kò sì lópin? O gba nǹkan ìdógò lọ́wọ́ àwọn arakunrin rẹ láìnídìí, O bọ́ wọn sí ìhòòhò goloto. O kò fún aláàárẹ̀ ní omi mu, o kọ̀ láti fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ. Ẹni tí ó lágbára gba ilẹ̀, ẹni tí ó lọ́lá sì ń gbé inú rẹ̀. O lé àwọn opó jáde lọ́wọ́ òfo, o sì ṣẹ́ aláìní baba lápá. Nítorí náà ni okùn dídẹ fi yí ọ ká, tí jìnnìjìnnì sì bò ọ́ lójijì. Ìmọ́lẹ̀ rẹ ti di òkùnkùn, o kò ríran, ìgbì omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀. “Ṣebí Ọlọrun wà lókè ọ̀run Ó ń wo àwọn ìràwọ̀ nísàlẹ̀ àní àwọn tí wọ́n ga jùlọ, bí ó ti wù kí wọ́n ga tó! Sibẹsibẹ ò ń bèèrè pé, ‘Kí ni Ọlọrun mọ̀?’ Ṣé ó lè ṣe ìdájọ́ láti inú òkùnkùn biribiri? Ìkùukùu tí ó nípọn yí i ká, tóbẹ́ẹ̀ tí kò lè ríran, ó sì ń rìn ní òfuurufú ojú ọ̀run. “Ṣé ọ̀nà àtijọ́ ni ìwọ óo máa tẹ̀lé; ọ̀nà tí àwọn ẹni ibi rìn? A gbá wọn dànù, kí àkókò wọn tó tó, a ti gbá ìpìlẹ̀ wọn lọ. Wọ́n sọ fún Ọlọrun pé, ‘Fi wá sílẹ̀, kí ni ìwọ Olodumare lè fi wá ṣe?’ Sibẹsibẹ ó fi ìṣúra dáradára kún ilé wọn— ṣugbọn ìmọ̀ràn ẹni ibi jìnnà sí mi. Àwọn olódodo rí i, inú wọn dùn, àwọn aláìlẹ́bi fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà, wọ́n ń wí pé, ‘Dájúdájú, àwọn ọ̀tá wa ti parun, iná sì ti jó gbogbo ohun tí wọ́n fi sílẹ̀.’ “Nisinsinyii gba ti Ọlọrun, kí o sì wà ní alaafia; kí ó lè dára fún ọ. Gba ìtọ́ni rẹ̀, kí o sì kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ lékàn. Bí o bá yipada sí Olodumare, tí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀, tí o bá mú ìwà aiṣododo kúrò ní ibùgbé rẹ, bí o bá ri wúrà mọ́ inú erùpẹ̀, tí o fi wúrà Ofiri sí ààrin àwọn òkúta ìsàlẹ̀ odò, bí Olodumare bá sì jẹ́ wúrà rẹ, ati fadaka olówó iyebíye rẹ, nígbà náà ni o óo láyọ̀ ninu Olodumare, o óo sì lè dúró níwájú Ọlọrun. Nígbà náà, o óo gbadura sí i, yóo sì gbọ́, o óo sì san ẹ̀jẹ́ rẹ. Ohunkohun tí o bá pinnu láti mú ṣe, yóo ṣeéṣe fún ọ, ìmọ́lẹ̀ yóo sì tàn sí ọ̀nà rẹ. Nítorí Ọlọrun a máa rẹ onigbeeraga sílẹ̀, a sì máa gba onírẹ̀lẹ̀. A máa gba àwọn aláìṣẹ̀, yóo sì gbà ọ́ là, nípa ìwà mímọ́ rẹ.” Nígbà náà ni Jobu dáhùn pé, “Lónìí, ìráhùn mi tún kún fún ẹ̀dùn, ọwọ́ Ọlọrun ń le lára mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mò ń kérora. Áà! Ìbá jẹ́ pé mo mọ ibi tí mo ti lè rí i ni, ǹ bá lọ siwaju ìtẹ́ rẹ̀! Ǹ bá ro ẹjọ́ mi níwájú rẹ̀, gbogbo ẹnu ni ǹ bá fi ṣàròyé. Ǹ bá gbọ́ èsì tí yóo fún mi, ati ọ̀rọ̀ tí yóo sọ fún mi. Ṣé yóo gbéjà kò mí pẹlu agbára ńlá rẹ̀? Rárá o, yóo gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi. Ibẹ̀ ni olódodo yóo ti lè sọ ti ẹnu rẹ̀, yóo sì dá mi sílẹ̀ títí lae. “Wò ó! Mo lọ siwaju, kò sí níbẹ̀, mo pada sẹ́yìn, n kò gbúròó rẹ̀. Mo wo apá ọ̀tún, n kò rí i, mo wo apá òsì, kò sí níbẹ̀. Ṣugbọn ó mọ gbogbo ọ̀nà mi, ìgbà tí ó bá dán mi wò tán, n óo yege bíi wúrà. Mò ń tẹ̀lé e lẹ́yìn, mo súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí, n kò tíì yipada kúrò ní ọ̀nà rẹ̀. N kò tíì yapa kúrò ninu àṣẹ tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde, mò ń pa wọ́n mọ́ ninu ọkàn mi. “Ṣugbọn Ọlọrun kìí yipada, kò sí ẹni tí ó lè yí i lọ́kàn pada. Ohun tí ó bá fẹ́ gan-an ni yóo ṣe. Yóo ṣe ohun tí ó ti pinnu láti ṣe fún mi ní àṣeyọrí, ati ọpọlọpọ nǹkan bẹ́ẹ̀ yòókù tí ó tún ní lọ́kàn láti ṣe fún mi. Ìdí nìyí tí ẹ̀rù fi bà mí níwájú rẹ̀, tí mo bá ro nǹkan wọnyi, jìnnìjìnnì rẹ̀ a bò mí. Ọlọrun ti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn mi, Olodumare ti dẹ́rùbà mí. Nítorí pé òkùnkùn yí mi ká, òkùnkùn biribiri sì ṣú bò mí lójú. “Kí ló dé tí Olodumare kò fi yan ọjọ́ ìdájọ́, kí àwọn tí wọ́n mọ̀ ọ́n sì rí ọjọ́ náà? “Àwọn eniyan a máa hú òkúta ààlà kúrò, láti gba ilẹ̀ ẹlòmíràn kún tiwọn, wọn a máa fi ipá sọ agbo ẹran ẹlòmíràn di tiwọn. Wọn a kó kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aláìníbaba lọ, wọn a gba akọ mààlúù opó gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò. Wọn a ti àwọn aláìní kúrò lójú ọ̀nà, gbogbo àwọn talaka a sì lọ sápamọ́. “Àwọn aláìní a máa ṣe làálàá káàkiri, bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ inú aṣálẹ̀, wọn a máa wá oúnjẹ fún àwọn ọmọ wọn ninu aṣálẹ̀. Wọn a máa kó oúnjẹ jọ fún ẹran wọn ninu oko olóko wọn a sì máa he èso àjàrà ní oko ìkà. Wọn a máa sùn ní ìhòòhò ní gbogbo òru, wọn kìí sìí rí aṣọ fi bora nígbà òtútù. Òjò a pa wọ́n lórí òkè, wọn a máa rọ̀ mọ́ àpáta nítorí àìsí ààbò. (Àwọn kan ń já àwọn ọmọ aláìníbaba gbà lẹ́nu ọmú, wọ́n sì ń gba ọmọ ọwọ́ lọ́wọ́ àwọn aláìní gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò.) Àwọn aláìní ń rìn kiri ní ìhòòhò láìrí aṣọ wọ̀; ebi ń pa wọ́n, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtí ọkà ni wọ́n rù. Wọ́n ń fún òróró lára èso olifi tí ó wà ní oko ìkà, òùngbẹ sì ń gbẹ wọ́n, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọtí ni wọ́n ń pọn. Àwọn tí wọn ń kú lọ ń kérora ní ìgboro, àwọn tí a pa lára ń ké fún ìrànlọ́wọ́, ṣugbọn Ọlọrun kò fetísí adura wọn. “A rí àwọn tí wọ́n kọ ìmọ́lẹ̀, tí wọn kò mọ ọ̀nà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúró ní ọ̀nà náà. Bí ilẹ̀ bá ṣú, apànìyàn á dìde, kí ó lè pa talaka ati aláìní, a sì dàbí olè ní òru. Alágbèrè pàápàá ń ṣọ́ kí ilẹ̀ ṣú, ó ń wí pé, ‘Kò sí ẹni tí yóo rí mi’; ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀. Lóru, wọn á máa lọ fọ́ ilé kiri, ṣugbọn bí ilẹ̀ bá ti mọ́, wọn á ti ìlẹ̀kùn mọ́rí, wọn kì í rí ìmọ́lẹ̀. Àárọ̀ ni òkùnkùn biribiri jẹ́ fún gbogbo wọn, ọ̀rẹ́ wọn ni òkùnkùn biribiri tí ó bani lẹ́rù.” Sofari dáhùn pé, “O sọ wí pé, ‘Ìṣàn omi a máa gbá àwọn ẹni ibi lọ kíákíá; ìpín tiwọn a sì di ìfibú ninu ilẹ̀ náà, ẹnikẹ́ni kìí sì í lọ sinu ọgbà àjàrà wọn láti ṣiṣẹ́ mọ́. Bí ọ̀gbẹlẹ̀ ati ooru ṣe máa ń mú kí omi yìnyín gbẹ bẹ́ẹ̀ ni ibojì ṣe ń gbé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ mì. Wọn á gbàgbé wọn láàrin ìlú, ẹnikẹ́ni kì í ranti orúkọ wọn mọ́, bẹ́ẹ̀ ni ẹni ibi ṣe é wó lulẹ̀ bí ìtì igi.’ Wọ́n ń jẹ oúnjẹ àgàn tí kò bímọ, wọn kò sì ṣe rere fún opó. Sibẹsibẹ Ọlọrun fi ẹ̀mí gígùn fún alágbára nípa agbára rẹ̀; wọn á gbéra nígbà tí ayé bá sú wọn. Ọlọrun ń dáàbò bò wọ́n, ó ń ràn wọ́n lọ́wọ́, ó sì ń pa wọ́n mọ́ ni ọ̀nà wọn. A gbé wọn ga fún ìgbà díẹ̀, lẹ́yìn náà, a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, wọn á rọ, wọn á sì rẹ̀ dànù bí ewé, a ké wọn kúrò bí orí ọkà bàbà. Bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, kí ẹnìkan já mi nírọ́, kí ó sì fi hàn pé ìsọkúsọ ni mò ń sọ.” Bilidadi ará Ṣuha bá dáhùn pé, “Ọlọrun ni ọba, òun ló sì tó bẹ̀rù, ó ń ṣe àkóso alaafia lọ́run. Ta ló lè ka àwọn ọmọ ogun rẹ̀? Ta ni ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kò tàn sí? Báwo wá ni eniyan ṣe lè jẹ́ olódodo níwájú Ọlọrun? Báwo ni ẹni tí obinrin bí ṣe lè jẹ́ ẹni mímọ́? Wò ó, òṣùpá pàápàá kò mọ́lẹ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìràwọ̀ kò mọ́ tó lójú rẹ̀; kí á má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti eniyan tí ó dàbí ìdin, tabi ọmọ eniyan tí ó dàbí ekòló lásánlàsàn!” Jobu bá dáhùn pé, “Ìrànlọ́wọ́ wo ni ẹ ti ṣe fún àwọn tí wọn kò lágbára? Aláìlera wo ni ẹ ti gbàlà? Ìmọ̀ràn wo ni ẹ ti fún àwọn aláìgbọ́n? Irú òye wo ni ẹ fihàn wọ́n? Ta ló ń kọ yín ni ohun tí ẹ̀ ń sọ wọnyi? Irú ẹ̀mí wo sì ní ń gba ẹnu yín sọ̀rọ̀? “Àwọn òkú wárìrì nísàlẹ̀. Omi ati àwọn olùgbé inú rẹ̀ pẹlu ń gbọ̀n rìrì. Kedere ni isà òkú rí níwájú Ọlọrun, bẹ́ẹ̀ ni ìparun kò farasin. Ó na ìhà àríwá sórí òfuurufú, ó sì so ayé rọ̀ sí òfuurufú. Ó di omi papọ̀ ninu ìkùukùu rẹ̀ tí ó nípọn, sibẹ ìkùukùu kò fà ya. Ó dí ojú òṣùpá, ó sì fi ìkùukùu bò ó. Ó ṣe òbìrìkítí kan sórí omi, ó fi ṣe ààlà láàrin òkùnkùn ati ìmọ́lẹ̀. Àwọn òpó ọ̀run mì tìtì, wọ́n sì wárìrì nítorí ìbáwí rẹ̀. Nípa agbára rẹ̀, ó mú kí òkun parọ́rọ́, nípa ìmọ̀ rẹ̀, ó pa Rahabu. Ó fi afẹ́fẹ́ ṣe ojú ọ̀run lọ́ṣọ̀ọ́; ọwọ́ ló fi pa ejò tí ń fò. Ṣugbọn kékeré nìyí ninu agbára rẹ̀, díẹ̀ ni a tíì gbọ́ nípa iṣẹ́ rẹ̀! Nítorí náà ta ló lè mọ títóbi agbára rẹ̀?” Jobu tún dáhùn pé, “Mo fi Ọlọrun tí ó gba ẹ̀tọ́ mi búra, mo fi Olodumare tí ó mú kí ọkàn mi bàjẹ́ ṣẹ̀rí, níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè, tí mo sì ń mí, n kò ní fi ẹnu mi purọ́, ahọ́n mi kò sì ní sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn. Kí á má rí i, n kò jẹ́ pè yín ní olóòótọ́; títí di ọjọ́ ikú mi ni n óo dúró lórí ọ̀rọ̀ mi, pé mo wà lórí àre. Mo dúró lórí òdodo mi láìyẹsẹ̀, ọkàn mi kò ní dá mi lẹ́bi, títí n óo fi kú. “Kí ó rí fún ọ̀tá mi gẹ́gẹ́ bí í ti í rí fún ẹni ibi, kí ó sì rí fún ẹni tí ó dojú kọ mí bí í ti í rí fún alaiṣododo. Ìrètí wo ni ẹni tí kò mọ Ọlọrun ní nígbà tí Ọlọrun bá pa á run, tí Ọlọrun sì gba ẹ̀mí rẹ̀? Ǹjẹ́ Ọlọrun yóo gbọ́ igbe rẹ̀, nígbà tí ìyọnu bá dé bá a? Ǹjẹ́ yóo ní inú dídùn sí Olodumare? Ǹjẹ́ yóo máa ké pe Ọlọrun nígbà gbogbo? “N óo kọ yín ní ìmọ̀ agbára Ọlọ́run; n kò sì ní fi ohun tíí ṣe ti Olodumare pamọ́. Wò ó! Gbogbo yín ni ẹ ti fojú yín rí i, kí ló wá dé tí gbogbo yín fí ń sọ ìsọkúsọ?” “Ìpín ẹni ibi láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun nìyí, òun ni ogún tí àwọn aninilára ń rí gbà lọ́dọ̀ Olodumare: Bí àwọn ọmọ rẹ̀ bá ń pọ̀ sí i, kí ogun baà lè pa wọ́n ni, oúnjẹ kò sì ní ká wọn lẹ́nu. Àwọn ọmọ tí wọn bá gbẹ̀yìn rẹ̀, àjàkálẹ̀ àrùn ni yóo pa wọ́n, àwọn opó wọn kò sì ní ṣọ̀fọ̀ wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń kó fadaka jọ bí erùpẹ̀, tí ó sì to aṣọ jọ bí amọ̀; olódodo ni yóo wọ aṣọ tí ó bá kó jọ, àwọn aláìṣẹ̀ ni yóo pín fadaka rẹ̀. Ilé tí ó kọ́ dàbí òwú aláǹtakùn, àní bí àgọ́ àwọn tí wọn ń ṣọ́nà. A ti máa wọlé sùn pẹlu ọrọ̀ tẹ́lẹ̀, ṣugbọn kò ní rí bẹ́ẹ̀ fún un mọ́. Nígbà tí ó bá la ojú rẹ̀, gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ yóo ti fò lọ. Ìwárìrì á bò ó mọ́lẹ̀ bí ìkún omi, ní alẹ́, ìjì líle á gbé e lọ. Afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn á fẹ́ ẹ sókè, á sì gbé e lọ, á gbá a kúrò ní ipò rẹ̀. Á dìgbò lù ú láìṣàánú rẹ̀, á sá lọ kúrò lọ́wọ́ agbára rẹ̀. Ọlọrun á pàtẹ́wọ́ lé e lórí, á sì pòṣé sí i láti ibi tí ó wà. “Dájúdájú, ibìkan wà tí wọ́n ti ń wa fadaka, ibìkan sì wà tí wọ́n ti ń yọ́ wúrà. Inú ilẹ̀ ni a ti ń wa irin, a sì ń yọ́ idẹ lára òkúta. Eniyan á sọ òkùnkùn di ìmọ́lẹ̀, a sì ṣe àwárí irin, ninu ọ̀gbun ati òkùnkùn biribiri. Wọn á gbẹ́ kòtò ninu àfonífojì, níbi tí ó jìnnà sí ibi tí eniyan ń gbé, àwọn arìnrìnàjò á gbàgbé wọn, wọn á takété sí àwọn eniyan, wọn á sì máa rọ̀ dirodiro sọ́tùn-ún sósì. Ní ti ilẹ̀, inú rẹ̀ ni oúnjẹ ti ń jáde, ṣugbọn lábẹ́ rẹ̀, ó dàbí ẹnipé iná ń yí i po, ó gbóná janjan. Safire ń bẹ ninu àwọn òkúta rẹ̀, wúrà sì ni erùpẹ̀ rẹ̀. Ẹyẹ àṣá kò mọ ipa ọ̀nà ibẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ojú gúnnugún kò tó o. Àwọn ẹranko onigbeeraga kò tíì tẹ ojú ọ̀nà náà, kinniun kò sì tíì gba ibẹ̀ kọjá rí. “Eniyan á dá ọwọ́ rẹ̀ lé òkúta akọ, á gbẹ́ ẹ, á sì hú òkè ńlá tìdítìdí. Á gbẹ́ ihò sinu àpáta, ojú rẹ̀ a sì tó àwọn ìṣúra iyebíye. Á dí orísun àwọn odò, tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò fi lè sun, á sì wá àwọn ohun tí ó pamọ́ jáde. Ṣugbọn níbo ni a ti lè rí ọgbọ́n? Níbo sì ni ìmọ̀ wà? “Ẹnikẹ́ni kò mọ ọ̀nà ibi tí ó wà; bẹ́ẹ̀ ni kò sí ní ilẹ̀ alààyè. Ibú sọ pé, ‘Kò sí ninu mi,’ òkun sì ní, ‘Kò sí lọ́dọ̀ mi.’ Wúrà iyebíye kò lè rà á, fadaka kò sì ṣe é díwọ̀n iye rẹ̀. A kò lè fi wúrà Ofiri díwọ̀n iye rẹ̀, tabi òkúta onikisi tabi safire tí wọ́n jẹ́ òkúta olówó iyebíye. Ọgbọ́n níye lórí ju wúrà ati dígí lọ, a kò lè fi ohun ọ̀ṣọ́ tí a fi wúrà dáradára ṣe dípò rẹ̀. Kí á má tilẹ̀ sọ ti iyùn tabi Kristali, ọgbọ́n ní iye lórí ju òkúta Pali lọ. A kò lè fi wé òkúta topasi láti ilẹ̀ Etiopia, tabi kí á fi ojúlówó wúrà rà á. “Níbo ni ọgbọ́n ti ń wá; níbo sì ni ìmọ̀ wà? Ó pamọ́ lójú gbogbo ẹ̀dá alààyè, ati lójú àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run. Ìparun ati ikú jẹ́wọ́ pé, ‘Àhesọ ni ohun tí a gbọ́ nípa rẹ̀.’ “Ọlọrun nìkan ló mọ ọ̀nà rẹ̀, òun nìkan ló mọ ibùjókòó rẹ̀. Nítorí pé ó ń wo gbogbo ayé, ó sì ń rí ohun gbogbo tí ó wà lábẹ́ ọ̀run. Nígbà tí ó fún afẹ́fẹ́ ní agbára, tí ó sì ṣe ìdíwọ̀n omi, nígbà tí ó pàṣẹ fún òjò, tí ó sì lànà fún mànàmáná. Lẹ́yìn náà ó rí i, ó sì sọ ọ́ jáde, ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, ó sì dán an wò. Nígbà náà ni ó sọ fún eniyan pé, ‘Wò ó, ìbẹ̀rù OLUWA ni ọgbọ́n, kí á yẹra fún ibi sì ni ìmọ̀.’ ” Jobu tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ báyìí pé, “Ìbá jẹ́ tún rí fún mi, bí ìgbà àtijọ́, nígbà tí Ọlọrun ń tọ́jú mi; nígbà tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ń tàn sí mi lórí, tí mo kọjá ninu òkùnkùn pẹlu ìmọ́lẹ̀ rẹ̀; kí ó tún rí fún mi bí ìgbà tí ara dẹ̀ mí, nígbà tí ìrẹ́pọ̀ wà láàrin Ọlọrun ati ìdílé mi; tí Olodumare wà pẹlu mi, tí gbogbo àwọn ọmọ mi yí mi ká; tí mò ń rí ọpọlọpọ wàrà lára àwọn ẹran ọ̀sìn mi, ati ọpọlọpọ òróró lára igi olifi tí ń dàgbà láàrin òkúta! Nígbà tí mo lọ sí ẹnubodè ìlú, tí mo jókòó ní gbàgede, tí àwọn ọdọmọkunrin bá rí mi, wọn á bìlà sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, àwọn àgbà á sì dìde dúró; àwọn ìjòyè á dákẹ́ rọ́rọ́, wọn á fi ọwọ́ bo ẹnu wọn. Àwọn olórí á panumọ́, ahọ́n wọn á lẹ̀ mọ́ wọn lẹ́nu. Àwọn tí wọ́n gbọ́ nípa mi, ń pè mí ní ẹni ibukun, àwọn tí wọ́n rí mi ń kan sáárá sí mi. Nítorí pé mò ń ran àwọn aláìní tí ń ké lọ́wọ́, ati àwọn aláìníbaba tí wọn kò ní olùrànlọ́wọ́. Ìre àwọn tí ń kú lọ mọ́ mi, mo sì mú kí opó kọrin ayọ̀. Mo fi òdodo bora bí aṣọ, ìdájọ́ òtítọ́ dàbí ẹ̀wù ati adé mi. Mo jẹ́ ojú fún afọ́jú, ati ẹsẹ̀ fún arọ. Mo jẹ́ baba fún talaka, mo gba ẹjọ́ àlejò rò. Mo ṣẹ́ ẹni ibi lápá, mo gba ẹni tí ó mú sílẹ̀. “Nígbà náà, mo rò pé, n óo gbòó, n óo tọ̀ọ́ láyé, ati pé inú ilé mi ni n óo sì kú sí. Mo ta gbòǹgbò lọ síbi omi, ìrì sì ń sẹ̀ sí ẹ̀ka mi ní alaalẹ́. Ọlá hàn lára mi, agbára mi sì ń di titun nígbà gbogbo. Àwọn eniyan á dákẹ́ jẹ́ẹ́, wọn á farabalẹ̀ gbọ́ tèmi, wọ́n sì ń gba ìmọ̀ràn mi pẹlu. Lẹ́yìn tí mo bá ti sọ̀rọ̀ tán, ẹnikẹ́ni kì í tún sọ̀rọ̀ mọ́, ọ̀rọ̀ mi a máa wọ̀ wọ́n lára. Wọ́n ń retí mi, bí ẹni retí òjò àkọ́rọ̀. Mo rẹ́rìn-ín sí wọn nígbà tí wọn ń ṣiyèméjì, wọn kò sì lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi. Mo jókòó bí ọba, mò ń tọ́ wọn sọ́nà, mo dàbí ọba láàrin àwọn ọmọ ogun rẹ̀, bí olùtùnú fún oníròbìnújẹ́. “Ṣugbọn nisinsinyii àwọn tí wọ́n kéré sí mi ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà, àwọn tí baba wọn kò tó fi wé àwọn ajá tí ń ṣọ́ agbo ẹran mi. Kí ni anfaani agbára wọn fún mi, àwọn tí wọn kò lókun ninu? Ninu ìyà ati ebi, wọ́n ń jẹ gbòǹgbò igi gbígbẹ káàkiri lálẹ́ ninu aṣálẹ̀. Ewé igi inú igbó ni wọ́n ń já jẹ, àní, àwọn igi ọwọ̀ tí kò ládùn kankan. Wọ́n lé wọn jáde láàrin àwọn eniyan, wọ́n ń hó lé wọn lórí bí olè. Wọ́n níláti máa gbé ojú àgbàrá, ninu ihò ilẹ̀, ati ihò àpáta. Wọ́n ń dún bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ninu igbó, wọ́n ń kó ara wọn jọ sí abẹ́ igi ẹlẹ́gùn-ún. Àwọn aláìlóye ọmọ, àwọn ọmọ eniyan lásán, àwọn tí a ti nà kúrò lórí ilẹ̀ náà. “Nisinsinyii mo ti di orin lẹ́nu wọn, mo ti di àmúpòwe. Mo di ẹni ìríra lọ́dọ̀ wọn, wọ́n ń rí mi sá, ara kò tì wọ́n láti tutọ́ sí mi lójú. Nítorí Ọlọrun ti sọ mí di aláìlera, ó sì ti rẹ̀ mí sílẹ̀, wọn dojú ìjà kọ mí ninu ibinu wọn. Àwọn oníjàgídíjàgan dìde sí mi ní apá ọ̀tún mi, wọ́n lé mi kúrò, wọ́n sì la ọ̀nà ìparun sílẹ̀ fún mi. Wọ́n dínà mọ́ mi, wọ́n dá kún wahala mi, kò sì sí ẹni tí ó lè dá wọn lẹ́kun. Wọ́n jálù mí, bí ìgbà tí ọpọlọpọ ọmọ ogun bá gba ihò ara odi ìlú wọlé, wọ́n ya lù mí, wọ́n wó mi mọ́lẹ̀. Ìbẹ̀rù-bojo dé bá mi, wọ́n ń lépa ọlá mi bí afẹ́fẹ́, ọlà mi sì parẹ́ bí ìkùukùu. “Nisinsinyii, ẹ̀mí mi fò lọ ninu mi, ọjọ́ ìjìyà sì dé bá mi. Ní òru, egungun ń ro mí, ìrora mi kò sì dínkù. Ọlọrun fi ipá gba aṣọ mi, ó fún mi lọ́rùn bí ọrùn ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ mi. Ó sọ mí sinu ẹrẹ̀, mo dàbí eruku ati eérú. “Mo ké pè ọ́, Ọlọrun, O kò dáhùn, mo dìde dúró, mo gbadura, o kò kà mí sí. O dojú ibinu kọ mí, o fi agbára rẹ bá mi jà. O sọ mí sókè ninu afẹ́fẹ́, ò ń bì mí síhìn-ín sọ́hùn-ún láàrin ariwo ìjì líle. Dájúdájú mo mọ̀ pé o óo gbé mi lọ sí ipò òkú, ilé tí o yàn fún gbogbo eniyan. Bí ẹni tí a ti là mọ́lẹ̀, tí kò lè dìde, bá ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ ninu ìnira, dájúdájú o kò tún ní gbé ìjà kò ó? Ṣebí mo ti sọkún nítorí àwọn tí wọ́n wà ninu ìṣòro rí, tí mo sì káàánú àwọn aláìní. Ṣugbọn nígbà tí mo bá ń retí ohun rere, ibi ní ń bá mi. Nígbà tí mo bá sì ń retí ìmọ́lẹ̀, òkùnkùn ni mò ń rí. Ọkàn mi dàrú, ara mi kò balẹ̀, ọjọ́ ìpọ́njú dé bá mi. Mo fa ojú ro, mò ń káàkiri, mo dìde nàró láti bèèrè ìrànlọ́wọ́ láàrin àwùjọ. Mò ń kígbe arò bí ajáko, mo di ẹgbẹ́ ẹyẹ ògòǹgò. Àwọ̀ ara mi di dúdú, ó ń bó, egungun mi gbóná fún ooru. Ọ̀fọ̀ dípò orin ayọ̀ fún mi, ẹkún sì dípò ohùn fèrè. “Mo ti bá ojú mi dá majẹmu; n óo ṣe wá máa wo wundia? Kí ni yóo jẹ́ ìpín mi lọ́dọ̀ Ọlọrun lókè? Kí ni ogún mi lọ́dọ̀ Olodumare? Ṣebí jamba a máa bá àwọn alaiṣododo, àjálù a sì máa dé bá àwọn oníṣẹ́-ẹ̀ṣẹ̀. Ṣebí Ọlọrun mọ ọ̀nà mi, ó sì mọ ìrìn mi. Bí mo bá rìn ní ọ̀nà aiṣododo, tí mo sì yára láti sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, (kí Ọlọrun gbé mi ka orí ìwọ̀n tòótọ́, yóo sì rí i pé olóòótọ́ ni mí!) Bí mo bá ti yí ẹsẹ̀ kúrò ní ọ̀nà tààrà, tí mò ń ṣe ojúkòkòrò, tí ọwọ́ mi kò sì mọ́, jẹ́ kí ẹlòmíràn kórè oko mi, kí o sì fa ohun ọ̀gbìn mi tu. “Bí ọkàn mi bá fà sí obinrin olobinrin, tabi kí n máa pẹ́ kọ̀rọ̀ lẹ́nu ọ̀nà aládùúgbò mi; jẹ́ kí iyawo mi máa se oúnjẹ fún ẹlòmíràn, kí ẹlòmíràn sì máa bá a lòpọ̀. Nítorí ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó burú jù, ẹ̀ṣẹ̀ tí adájọ́ gbọdọ̀ jẹ mí níyà fún. Iná ajónirun ni, tí yóo run gbogbo ohun ìní mi kanlẹ̀. “Bí mo bá kọ̀ láti fetí sí ẹjọ́ àwọn iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin mi, nígbà tí wọ́n bá fẹ̀sùn kàn mí, báwo ni n óo ṣe dúró níwájú Ọlọrun? Kí ni kí n wí nígbà tí ó bá bèèrè lọ́wọ́ mi? Ṣebí ẹni tí ó dá mi ninu oyún, òun kan náà ló dá iranṣẹ mi? Òun ló mọ wá kí wọn tó bí wa. “Bí mo bá fi ohunkohun pọ́n talaka lójú rí, tabi kí n fi opó sílẹ̀ ninu àìní, tabi kí n dá oúnjẹ mi jẹ, láìfún ọmọ aláìníbaba jẹ (láti ìgbà èwe rẹ̀ ni mo ti ń ṣe bíi baba fún un, tí mo sì ń tọ́jú rẹ̀ láti inú ìyá rẹ̀); bí mo bá ti rí ẹni tí ó ń kú lọ, nítorí àìrí aṣọ bora, tabi talaka tí kò rí ẹ̀wù wọ̀, kí ó sì súre fún mi, nítorí pé ara rẹ̀ móoru pẹlu aṣọ tí a fi irun aguntan mi hun, bí mo bá fi ìyà jẹ aláìníbaba, nítorí pé mo mọ eniyan ní ilé ẹjọ́, jẹ́ kí apá mi já kúrò léjìká mi, kí ó yọ ní oríkèé rẹ̀. Nítorí ẹ̀rù ìpọ́njú láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ń bà mí, nítorí ògo rẹ̀, n kò lè dán irú rẹ̀ wò. “Bí mo bá gbójú lé wúrà, tí mo sì fi ojúlówó wúrà ṣe igbẹkẹle mi, bí mo bá ń yọ̀ nítorí pé mo ní ọrọ̀ pupọ, tabi nítorí pé ọwọ́ mi ti ba ọpọlọpọ ohun ìní. Tí mo bá ti wo oòrùn nígbà tí ó ń ràn, tabi tí mo wo òṣùpá ninu ẹwà rẹ̀: tí ọkàn mi fà sí wọn; tí mo sì tẹ́wọ́ adura sí wọn. Èyí pẹlu yóo jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, tí adájọ́ gbọdọ̀ jẹ mí níyà fún; nítorí yóo jẹ́ aiṣootọ sí Ọlọrun ọ̀run. “Bí mo bá yọ̀ nítorí ìparun ẹni tí ó kórìíra mi, tabi kí inú mi dùn nígbà tí ohun burúkú bá ṣẹlẹ̀ sí i. (N kò fi ẹnu mi ṣẹ̀ kí n gbé e ṣépè pé kí ó lè kú); bí àwọn tí wọn ń gbé inú àgọ́ mi kò bá wí pé, ‘Ta ló kù tí kò tíì yó?’ (Kò sí àlejò tí ń sun ìta gbangba, nítorí ìlẹ̀kùn ilé mi ṣí sílẹ̀ fún àwọn arìnrìnàjò); bí mo bá fi ẹ̀ṣẹ̀ mi pamọ́ fún eniyan, tí mo sì dé àìdára mi mọ́ra, nítorí pé mò ń bẹ̀rù ọpọlọpọ eniyan, ẹ̀gàn ìdílé sì ń dẹ́rùbà mí, tóbẹ́ẹ̀ tí mo fi dákẹ́, tí n kò sì jáde síta. Ha! Ǹ bá rí ẹni gbọ́ tèmi! (Mo ti tọwọ́ bọ̀wé, kí Olodumare dá mi lóhùn!) Ǹ bá lè ní àkọsílẹ̀ ẹ̀sùn tí àwọn ọ̀tá fi kàn mí! Dájúdájú, ǹ bá gbé e lé èjìká mi, ǹ bá fi dé orí bí adé; ǹ bá sọ gbogbo ìgbésẹ̀ mi fún Ọlọrun, ǹ bá bá a sọ̀rọ̀ bí ìjòyè. “Bí ilẹ̀ mi bá kígbe ẹ̀san lé mi lórí, tí àwọn poro oko mi sì ń sọkún; tí mo bá jẹ ninu ìkórè ilẹ̀ náà láìsanwó rẹ̀, tabi tí mo sì ṣe ikú pa ẹni tí ó ni ín, kí ẹ̀gún hù lórí ilẹ̀ náà dípò ọkà, kí koríko hù dípò ọkà baali.” Ọ̀rọ̀ Jobu parí síhìn-ín. Àwọn ọkunrin mẹtẹẹta náà kò dá Jobu lóhùn mọ́, nítorí pé ó jẹ́ olódodo lójú ara rẹ̀. Elihu, ọmọ Barakeli, ará Busi, ní ìdílé Ramu bá bínú sí Jobu, nítorí pé ó dá ara rẹ̀ láre dípò Ọlọrun. Ó bínú sí àwọn ọ̀rẹ́ Jobu mẹtẹẹta pẹlu, nítorí pé wọn kò mọ èsì tí wọ́n lè fún Jobu mọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n dá a lẹ́bi. Elihu ti fẹ́ bá Jobu sọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀, ṣugbọn ó dákẹ́, nítorí àwọn àgbà tí wọ́n jù ú lọ ni wọ́n ń sọ̀rọ̀. Ṣugbọn nígbà tí Elihu rí i pé àwọn mẹtẹẹta kò lè fún Jobu lésì mọ́, inú bí i. Ó ní, “Àgbàlagbà ni yín, ọmọde sì ni mí, nítorí náà ni ojú fi ń tì mí, tí ẹ̀rù sì ń bà mí láti sọ èrò ọkàn mi. Mo ní kí ẹ̀yin àgbà sọ̀rọ̀, kí ọ̀rọ̀ yín sì fa ọgbọ́n yọ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí yín. Ṣugbọn ẹ̀mí tí ó wà ninu eniyan, tíí ṣe èémí Olodumare, ni ó ń fún eniyan ní ìmọ̀. Kì í ṣe àwọn àgbà nìkan ni wọ́n gbọ́n, tabi pé arúgbó nìkan ni ó mọ òye ohun tó tọ́, tó yẹ. Nítorí náà, ‘Ẹ fetí sílẹ̀, kí èmi náà lè sọ èrò ọkàn mi.’ “Mo farabalẹ̀ nígbà tí ẹ̀yin ń sọ̀rọ̀, mo fetí sí ọ̀rọ̀ ọgbọ́n yín, nígbà tí ẹ̀ ń ronú ohun tí ẹ fẹ́ sọ, Mo farabalẹ̀ fun yín, ṣugbọn kò sí ẹnikẹ́ni ninu yín tí ó lè ko Jobu lójú, kí ó sì fi àṣìṣe rẹ̀ hàn án, tabi kí ó fún un lésì àwọn àwíjàre rẹ̀. Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má baà wí pé, ‘A ti di ọlọ́gbọ́n, Ọlọrun ló lè ṣe ìdájọ́ rẹ̀, kì í ṣe eniyan.’ Èmi kọ́ ni Jobu ń bá wí, ẹ̀yin ni, n kò sì ní dá a lóhùn bí ẹ ṣe dá a lóhùn. “Ọkàn wọn dàrú, wọn kò sì lè fèsì mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ohun kan láti sọ. Ṣé kí n dúró, nítorí pé wọ́n dúró láìfèsì? Èmi náà óo fèsì lé e, n óo sì sọ èrò ọkàn tèmi. Mo ní ọ̀rọ̀ pupọ láti sọ, Ṣugbọn ẹ̀mí tí ó wà ninu mi ló ń kó mi ní ìjánu. Ọ̀rọ̀ kún inú mi bí ọtí inú ìgò, ó fẹ́ ru síta bí ọtí inú ìgò aláwọ. Mo níláti sọ̀rọ̀ kí ara lè rọ̀ mí, mo gbọdọ̀ la ẹnu mi kí n sì dáhùn. N kò ní ṣe ojuṣaaju ẹnikẹ́ni, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì ní gbèjà eniyan. Nítorí n kò mọ bí wọ́n ṣe ń pọ́n eniyan, kí Ẹlẹ́dàá mi má baà pa mí run ní kíá. “Jobu, tẹ́tí sílẹ̀ nisinsinyii kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Wò ó! Mo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ sì pọ̀ tí mo fẹ́ sọ. Òtítọ́ inú ni mo fi fẹ́ sọ̀rọ̀, ohun tí mo mọ̀ pé òdodo ni ni mo sì fẹ́ sọ. Ẹ̀mí Ọlọrun ni ó dá mi, èémí Olodumare ni ó sì fún mi ní ìyè. “Bí o bá lè dá mi lóhùn, dáhùn. Ro ohun tí o fẹ́ sọ dáradára, kí o sì múra láti wí àwíjàre. Wò ó, bákan náà ni èmi pẹlu rẹ rí lójú Ọlọrun, amọ̀ ni a fi mọ èmi náà. Má jẹ́ kí ẹ̀rù mi bà ọ́, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní le kankan mọ́ ọ. “Lóòótọ́, o ti sọ̀rọ̀ ní etígbọ̀ọ́ mi, mo sì ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ. O ní o mọ́, o kò ní ẹ̀ṣẹ̀, ara rẹ mọ́ o kò sì ṣe àìdára kankan. Sibẹ Ọlọrun wá ẹ̀sùn sí ọ lẹ́sẹ̀, ó sọ ọ́ di ọ̀tá rẹ̀, ó kan ààbà mọ́ ọ lẹ́sẹ̀, ó sì ń ṣọ́ ìrìn rẹ. “Jobu, n óo dá ọ lóhùn, nítorí pé bí o ti wí yìí, bẹ́ẹ̀ kọ́ lọ̀rọ̀ rí. Ọlọrun ju eniyan lọ. Kí ló dé tí ò ń fi ẹ̀sùn kàn án pé kò ní fèsì kankan sí ọ̀rọ̀ rẹ? Nítorí Ọlọrun sọ̀rọ̀ bákan, ó tún tún un sọ bámìíràn, ṣugbọn kò sí ẹni tí ó yé. Ninu àlá, lójú ìran ní ààrin òru, nígbà tí eniyan bá sun oorun àsùnwọra, lórí ibùsùn wọn, Ọlọrun a máa ṣí wọn létí, a máa kìlọ̀ fún wọn, a sì máa dẹ́rùbà wọ́n, kí ó lè dá wọn lẹ́kun ìṣe wọn, kí ó lè gba ìgbéraga lọ́wọ́ wọn; kí ó lè yọ ọkàn eniyan kúrò ninu ọ̀fìn ìparun, kí ó má baà kú ikú idà. “OLUWA a máa fi ìrora jẹ eniyan níyà lórí ibùsùn rẹ̀; a sì máa kó ìnira bá egungun rẹ̀. Tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnu rẹ̀ yóo kọ oúnjẹ, oúnjẹ àdídùn óo sì rùn sí i. Eniyan á rù hangangan, wọn a sì fẹ́rẹ̀ lè máa ka egungun rẹ̀. Ọkàn rẹ̀ á súnmọ́ ibojì, ẹ̀mí rẹ̀ a sì súnmọ́ àwọn iranṣẹ ikú. Bí angẹli kan bá wà pẹlu rẹ̀, tí ó wà fún un bí onídùúró, àní, ọ̀kan láàrin ẹgbẹrun, tí yóo sọ ohun tí ó tọ́ fún un, tí yóo ṣàánú rẹ̀, tí yóo sì wí pé, ‘Ẹ gbà á sílẹ̀, ẹ má jẹ́ kí ó lọ sinu ibojì, mo ti rí ìràpadà kan dípò rẹ̀.’ Jẹ́ kí àwọ̀ rẹ̀ jọ̀lọ̀ bí ara ọmọde, kí agbára rẹ̀ sì pada dàbí ti ìgbà ọ̀dọ́; nígbà náà eniyan óo gbadura sí Ọlọrun, Ọlọrun óo sì gbọ́ adura rẹ̀. Eniyan óo wá fi ayọ̀ wá siwaju Ọlọrun, yóo sì ròyìn ìgbàlà Ọlọrun fún gbogbo aráyé Yóo wá sọ gbangba níwájú àwọn eniyan pé, ‘Mo ti ṣẹ̀, mo sì ti yí ẹ̀tọ́ po, ṣugbọn Ọlọrun kò jẹ mí níyà ẹ̀ṣẹ̀ mi. Ó ti ra ọkàn mi pada kúrò lọ́wọ́ isà òkú, mo sì wà láàyè.’ “Wò ó, Ọlọrun a máa ṣe nǹkan wọnyi léraléra fún eniyan, lẹẹmeji tabi lẹẹmẹta, láti lè gba ọkàn rẹ̀ là lọ́wọ́ ikú, kí ó lè wà láàyè. “Gbọ́, ìwọ Jobu, farabalẹ̀, dákẹ́ kí o lè gbọ́ ohun tí n óo sọ. Bí o bá ní ohunkohun láti sọ, dá mi lóhùn; sọ̀rọ̀, nítorí pé mo fẹ́ dá ọ láre ni. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, tẹ́tí sí mi; farabalẹ̀, n óo sì kọ́ ọ lọ́gbọ́n.” Elihu tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ bọ̀, ó ní, “Ẹ gbọ́rọ̀ mi, ẹ̀yin ọlọ́gbọ́n, ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin tí ẹ ní ìmọ̀, nítorí bí ahọ́n ti í máa ń tọ́ oúnjẹ wò, bẹ́ẹ̀ ni etí náà lè máa tọ́ ọ̀rọ̀ wò Ẹ jẹ́ kí á yan ohun tí ó tọ́, kí á jọ jíròrò ohun tí ó dára láàrin ara wa. Jobu sọ pé òun kò jẹ̀bi, ó ní Ọlọrun ni ó kọ̀ tí kò dá òun láre. Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun jàre, Ọlọrun ka òun kún òpùrọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kò dẹ́ṣẹ̀, ọgbẹ́ òun kò ṣe é wòsàn. “Ta ló dàbí Jobu, tí ń kẹ́gàn Ọlọrun nígbà gbogbo, tí ó ń bá àwọn aṣebi kẹ́gbẹ́, tí ó sì ń bá àwọn eniyan burúkú rìn? Nítorí ó ń sọ pé, ‘Kò sí èrè kankan, ninu ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọrun.’ “Nítorí náà ẹ gbọ́ tèmi, ẹ̀yin olóye, Ọlọrun kì í ṣe ibi, Olodumare kì í ṣe ohun tí kò tọ́. Nítorí a máa san ẹ̀san fún eniyan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ ati gẹ́gẹ́ bí ìwà rẹ̀. Nítòótọ́, Ọlọrun kì í ṣe ibi, bẹ́ẹ̀ ni Olodumare kì í dájọ́ èké. Ta ló fi í ṣe alákòóso ayé, ta ló sì fi jẹ olórí gbogbo ayé? Bí Ọlọrun bá gba ẹ̀mí rẹ̀ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, tí ó sì gba èémí rẹ̀ pada sọ́dọ̀, gbogbo eniyan ni yóo ṣègbé, tí wọn yóo sì pada di erùpẹ̀. “Bí ẹ bá ní òye, ẹ gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ. Ǹjẹ́ ẹni tí ó kórìíra ìdájọ́ ẹ̀tọ́ lè jẹ́ olórí? Àbí ẹ lè dá olódodo ati alágbára lẹ́bi? Ẹni tí ó tó pe ọba ní eniyan lásán, tí ó tó pe ìjòyè ní ẹni ibi; ẹni tí kì í ṣe ojuṣaaju fún àwọn ìjòyè, tí kì í sì í ka ọlọ́rọ̀ sí ju talaka lọ, nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn. Wọn á kú ikú òjijì, ní ọ̀gànjọ́ òru; á mi gbogbo eniyan jìgìjìgì, wọn a sì kú. Ikú á mú àwọn alágbára lọ láì jẹ́ pé eniyan fi ọwọ́ kàn wọ́n. Nítorí pé ojú rẹ̀ tó gbogbo ọ̀nà tí eniyan ń tọ̀, ó sì rí gbogbo ìrìn ẹsẹ̀ wọn. Kò sí ibi òkùnkùn biribiri kankan, tí àwọn eniyan burúkú lè fi ara pamọ́ sí. Nítorí Ọlọrun kò nílò láti yan àkókò kan fún ẹnikẹ́ni, láti wá siwaju rẹ̀ fún ìdájọ́. Á pa àwọn alágbára run láìṣe ìwádìí wọn, á sì fi àwọn ẹlòmíràn dípò wọn. Nítorí pé ó mọ iṣẹ́ ọwọ́ wọn, á bì wọ́n ṣubú lóru, wọn á sì parun. Á máa jẹ wọ́n níyà ní gbangba, nítorí ìwà ibi wọn. Nítorí pé wọ́n kọ̀ láti tẹ̀lé e, wọn kò náání ọ̀nà rẹ̀ kankan, wọ́n ń jẹ́ kí àwọn talaka máa kígbe sí Ọlọrun, a sì máa gbọ́ igbe àwọn tí a ni lára. “Bí Ọlọrun bá dákẹ́, ta ló lè bá a wí? Nígbà tí ó bá fi ojú pamọ́, orílẹ̀-èdè tabi eniyan wo ló lè rí i? Kí ẹni ibi má baà lè ṣe àkóso, kí ó má baà kó àwọn eniyan sinu ìgbèkùn. “Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tíì sọ fún Ọlọrun pé, ‘Mo ti jìyà rí, n kò sì ní gbẹ̀ṣẹ̀ mọ́. Kọ́ mi ní ohun tí n kò rí, bí mo bá ti ṣẹ̀ rí, n kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́?’ Ṣé yóo san ẹ̀san fún ọ lọ́nà tí ó tẹ́ ọ lọ́rùn, nítorí pé o kọ̀ ọ́? Nítorí ìwọ ni o gbọdọ̀ yan ohun tí ó bá wù ọ́, kì í ṣe èmi, nítorí náà, sọ èrò ọkàn rẹ fún wa. Àwọn tí wọ́n lóye yóo sọ fún mi, àwọn ọlọ́gbọ́n tí wọn ń gbọ́ mi yóo sọ pẹlu pé, ‘Jobu ń sọ̀rọ̀ láìní ìmọ̀, ó ń sọ̀rọ̀ láìní òye tí ó jinlẹ̀.’ À bá lè gbé ọ̀rọ̀ Jobu yẹ̀wò títí dé òpin, nítorí pé ó ń sọ̀rọ̀ bí eniyan burúkú. Ó fi ọ̀tẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá; ó ń pàtẹ́wọ́ ẹlẹ́yà láàrin wa, ó sì ń kẹ́gàn Ọlọrun.” Elihu tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ bọ̀, ó ní, “Jobu, ṣé o rò pé ó tọ̀nà, kí o máa sọ pé, ‘Ọ̀nà mi tọ́ níwájú Ọlọrun?’ Kí o tún máa bèèrè pé, ‘Anfaani wo ni mo ní? Tabi kí ni mo fi sàn ju ẹni tí ó dẹ́ṣẹ̀ lọ?’ N óo dá ìwọ ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ lóhùn. Gbójú sókè kí o wo ojú ọ̀run, ati àwọn ìkùukùu tí ó wà lókè. Bí o bá dẹ́ṣẹ̀, kò ṣe Ọlọrun ní àìrójú, bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ bá pọ̀, kò jámọ́ nǹkankan fún un. Bí o bá jẹ́ olódodo, kí ni ó dà fún Ọlọrun, tabi kí ni ó ń rí gbà lọ́wọ́ rẹ? Àwọn eniyan burúkú bíì rẹ, ni ẹ̀ṣẹ̀ rẹ lè pa lára, àwọn ọmọ eniyan ni òdodo rẹ sì lè jẹ́ anfaani fún. “Àwọn eniyan ń kígbe nítorí ọpọlọpọ ìnira, wọ́n ń bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́, nítorí àwọn alágbára ń tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀. Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó bèèrè pé, ‘Níbo ni Ọlọrun Ẹlẹ́dàá mi wà, tíí fún ni ní orin ayọ̀ lóru, ẹni tí ó ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ ju àwọn ẹranko lọ, Ó sì fún wa ní ọgbọ́n ju àwọn ẹyẹ lọ?’ Wọ́n kígbe níbẹ̀ ṣugbọn kò dá wọn lóhùn, nítorí ìgbéraga àwọn eniyan burúkú. Dájúdájú Ọlọrun kì í gbọ́ igbe asán, Olodumare kò tilẹ̀ náání rẹ̀. Kí á má tilẹ̀ sọ ti ìwọ Jobu, tí o sọ pé o kò rí i, ati pé ẹjọ́ rẹ wà níwájú rẹ̀, o sì ń dúró dè é! Ṣugbọn nisinsinyii, nítorí pé inú kì í bí i kí ó jẹ eniyan níyà, bẹ́ẹ̀ ni kò ka ẹ̀ṣẹ̀ kún lọ títí. Jobu kàn ń la ẹnu, ó sì ń sọ̀rọ̀ lásán ni. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pọ̀, ṣugbọn kò mú ọgbọ́n lọ́wọ́.” Elihu tún tẹ̀síwájú ninu ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní, “Ní sùúrù fún mi díẹ̀, n óo ṣe àlàyé fún ọ, nítorí mo ní ohun kan tí mo fẹ́ gbẹnusọ fún Ọlọrun. N óo gba ìmọ̀ mi láti ọ̀nà jíjìn, n óo sì fi júbà Ẹlẹ́dàá mi, tí ó ní ìmọ̀ òdodo. Nítorí òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ mi; ẹni tí ìmọ̀ rẹ̀ péye ni èmi tí mò ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí. “Ọlọrun lágbára, kì í kẹ́gàn ẹnikẹ́ni, agbára ati òye rẹ̀ pọ̀ gan-an. Kì í jẹ́ kí eniyan burúkú ó wà láàyè, ṣugbọn a máa fún ẹni tí ìyà ń jẹ ní ẹ̀tọ́ rẹ̀. Kìí mú ojú kúrò lára àwọn olódodo, ṣugbọn a máa gbé wọn sórí ìtẹ́ pẹlu àwọn ọba, á gbé wọn ga, á sì fi ìdí wọn múlẹ̀ títí lae. Ṣugbọn bí a bá fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè wọ́n, tí ayé wọn kún fún ìpọ́njú, a máa fi àṣìṣe wọn hàn wọ́n, ati ẹ̀ṣẹ̀ ìgbéraga wọn. Ó fún wọn ní etígbọ̀ọ́, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀. Bí wọ́n bá gbọ́ràn, tí wọ́n sì sìn ín, wọn yóo lo ọjọ́ ayé wọn pẹlu ìdẹ̀rùn, wọn yóo ṣe ọ̀pọ̀ ọdún ninu ìgbádùn. Ṣugbọn bí wọn kò bá gbọ́ràn, a óo fi idà pa wọ́n, wọn yóo sì kú láìní ìmọ̀. “Àwọn tí kò mọ Ọlọrun fẹ́ràn ibinu, wọn kì í kígbe fún ìrànlọ́wọ́, nígbà tí ó bá fi wọ́n sinu ìdè. Wọn á kú ikú ìtìjú, nígbà tí wọ́n wà ní èwe. A máa lo ìpọ́njú àwọn tí à ń pọ́n lójú láti gbà wọ́n là, a sì máa lo ìdààmú wọn láti ṣí wọn létí. A máa yọ ọ́ kúrò ninu ìpọ́njú, bọ́ sinu ìdẹ̀ra níbi tí kò sí wahala, oúnjẹ tí a gbé kalẹ̀ níwájú rẹ̀ a sì jẹ́ kìkì àdídùn. “Ṣugbọn, ìdájọ́ eniyan burúkú dé bá ọ, ọwọ́ ìdájọ́ ati òdodo sì ti tẹ̀ ọ́. Ṣọ́ra kí ibinu má baà sọ ọ́ di ẹlẹ́yà, kí títóbi àbẹ̀tẹ́lẹ̀ sì mú ọ ṣìnà. Igbe ati agbára rẹ kò lè gbà ọ́ kúrò ninu ìpọ́njú. Má máa dúró, kí o máa retí ọjọ́ alẹ́, nígbà tí à ń pa àwọn eniyan run. Ṣọ́ra kí o má yipada sí ìwà ẹ̀ṣẹ̀, tí ó wù ọ́ ju ìjìyà lọ. “Wò ó, a gbé OLUWA ga ninu agbára rẹ̀; ta ni olùkọ́ tí ó dàbí rẹ̀? Ta ló ń sọ ohun tí yóo ṣe fún un, tabi kí ó sọ fún un pé, ‘Ohun tí o ṣe yìí kò dára?’ Ranti láti gbé iṣẹ́ rẹ̀ ga, tí àwọn eniyan ń kọrin nípa rẹ̀. Gbogbo eniyan ti rí i; àwọn tí wọ́n wà ní òkèèrè ń wò ó. Wò ó, Ọlọrun tóbi lọ́ba, ju ìmọ̀ wa lọ, kò sí ẹni tí ó lè mọ ọjọ́ orí rẹ̀. “Ó fa ìkán omi sókè láti inú ilẹ̀, ó sọ ìkùukùu di òjò, ó sì rọ òjò sílẹ̀ láti ojú ọ̀run sórí ọmọ eniyan lọpọlọpọ. Ta ló mọ bí ó ti tẹ́ ìkùukùu? Tabi bí ó ṣe ń sán ààrá láti inú àgọ́ rẹ̀? Ó fi mànàmáná yí ara rẹ̀ ká, ó sì bo ìsàlẹ̀ òkun mọ́lẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe ń ṣàkóso àwọn orílẹ̀-èdè; ó sì ń fún wọn ní oúnjẹ lọpọlọpọ. Ìkáwọ́ rẹ̀ ni mànàmáná wà, ó sì ń rán ààrá láti sán lu ohun tí ó bá fẹ́. Ìró ààrá ń kéde bíbọ̀ rẹ̀, àwọn ẹran ọ̀sìn sì mọ̀ pé ó súnmọ́ tòsí. “Nígbà tí mo gbọ́, ọkàn mi wárìrì, ó sì fò sókè ní ipò rẹ̀. Gbọ́ ohùn rẹ̀ tí ń dún bí ààrá, ati ariwo tí ń ti ẹnu rẹ̀ jáde. Ó rán mànàmáná rẹ̀ sí wọn jákèjádò ojú ọ̀run, títí dé òpin ilẹ̀ ayé. Lẹ́yìn náà, a gbọ́ ìró ohùn rẹ̀, ó sọ̀rọ̀ ninu ọlá ńlá rẹ̀, bí ìgbà tí ààrá bá sán, sibẹsibẹ kò dá mànàmáná dúró bí àwọn eniyan ti ń gbóhùn rẹ̀. Ohùn Ọlọrun dún bí ààrá tìyanu-tìyanu, a kò lè rí ìdí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀. Ó pàṣẹ pé kí yìnyín rọ̀ sórí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni òjò wẹliwẹli, ati ọ̀wààrà òjò. Ó ká gbogbo eniyan lọ́wọ́ iṣẹ́ kò, kí wọ́n lè mọ iṣẹ́ rẹ̀. Àwọn ẹranko wọ ihò wọn lọ, wọ́n dákẹ́ sibẹ, wọ́n sá pamọ́. Ìjì líle fẹ́ jáde láti inú yàrá rẹ̀, òtútù sì mú wá láti inú afẹ́fẹ́ tí ń fẹ́. Yìnyín ti inú èémí Ọlọrun wá, gbogbo omi inú odò sì dì. Ó fi omi kún inú ìkùukùu, ìkùukùu sì fọ́n mànàmáná rẹ̀ ká. Wọ́n ń yípo lábẹ́ ìtọ́ni rẹ̀, láti mú gbogbo àṣẹ tí ó pa ṣẹ, lórí ilẹ̀ alààyè. Ó mú kí àwọn nǹkan wọnyi ṣẹlẹ̀, bóyá fún àtúnṣe ni, tabi nítorí ilẹ̀ rẹ̀, tabi láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn. “Fetí sílẹ̀, ìwọ Jobu, dúró kí o sì ronú nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu Ọlọrun. Ǹjẹ́ o mọ bí Ọlọrun ṣe pàṣẹ, tí ó sì mú kí mànàmáná awọsanma tàn? Ǹjẹ́ o mọ̀ bí ó ṣe so awọsanma rọ̀, iṣẹ́ ìyanu ẹni tí ó pé ní ìmọ̀ ni; ìwọ tí ooru mú nígbà tí ayé dákẹ́ rọ́rọ́ nítorí pé afẹ́fẹ́ ìhà gúsù kò fẹ́? Ṣé o lè tẹ́ ojú ọ̀run bí ó ti tẹ́ ẹ, kí ó le, kí ó sì dàbí dígí tí ń dán? Kọ́ wa ní ohun tí a lè bá Ọlọrun sọ, a kò lè kó àròyé wa jọ siwaju rẹ̀, nítorí àìmọ̀kan wa. Ṣé kí n sọ fún Ọlọrun pé n ó bá a sọ̀rọ̀ ni? Ta ni yóo fẹ́ kí á gbé òun mì? “Ẹnikẹ́ni kò lè wo ìmọ́lẹ̀ ojú ọ̀run nígbà tí ó bá ń tàn ní awọsanma, nígbà tí afẹ́fẹ́ bá fẹ́ tí ó sì gbá wọn lọ. Láti ìhà àríwá ni Ọlọrun ti yọ, ó fi ọlá ńlá, tí ó bani lẹ́rù, bora bí aṣọ. Àwámárìídìí ni Olodumare— agbára ati ìdájọ́ òtítọ́ rẹ̀ pọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì í kọ òdodo sílẹ̀. Nítorí náà, gbogbo eniyan bẹ̀rù rẹ̀, kò sì náání àwọn tí wọ́n gbọ́n lójú ara wọn.” Nígbà náà ni OLUWA dá Jobu lóhùn láti inú ìjì líle. Ó bi í pé, “Ta ni ẹni tí ń bu ẹnu àtẹ́ lu ìmọ̀ràn, tí ń sọ̀rọ̀ tí kò ní ìmọ̀? Nisinsinyii, múra gírí bí ọkunrin, mo ní ìbéèrè kan láti bí ọ, o óo sì dá mi lóhùn. Níbo lo wà, nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀? Bí o bá mọ ìgbà náà, sọ fún mi. Ta ló ṣe ìdíwọ̀n rẹ̀— ṣebí o mọ̀ ọ́n, dá mi lóhùn! Àbí ta ló ta okùn ìwọ̀n sórí rẹ̀? Orí kí ni a gbé ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé, àbí ta ló fi òkúta igun rẹ̀ sọlẹ̀; tí àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ ń jùmọ̀ kọrin, tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọrun sì búsáyọ̀? Ta ló tìlẹ̀kùn mọ́ òkun, nígbà tí ó ń ru jáde, tí mo fi awọsanma ṣe ẹ̀wù rẹ̀, tí òkùnkùn biribiri sì jẹ́ ọ̀já ìgbànú rẹ̀, tí mo sì pa ààlà fún un, tí mo sé ìlẹ̀kùn mọ́ ọn, tí mo wí pé, ‘Dúró níhìn-ín, o kò gbọdọ̀ kọjá ibẹ̀, ibí ni ìgbì líle rẹ ti gbọdọ̀ dáwọ́ dúró?’ Jobu, láti ọjọ́ tí o ti dé ayé, ǹjẹ́ o ti pàṣẹ pé kí ilẹ̀ mọ́ rí, tabi pé kí àfẹ̀mọ́jú mọ́ àkókò rẹ̀, kí ìmọ́lẹ̀ lè tàn sí gbogbo ayé, kí ó sì lè gbọn àwọn ẹni ibi dànù, kúrò ní ibi ìsápamọ́sí wọn? A ti yí ayé pada bí amọ̀ tí a fi òǹtẹ̀ tẹ̀, ati bí aṣọ tí a pa láró. A mú ìmọ́lẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹni ibi, a sì ká wọn lápá kò. “Ṣé o ti wọ orísun òkun lọ rí, tabi o ti rìn nísàlẹ̀ ibú rí? Ṣé a ti fi ìlẹ̀kùn ikú hàn ọ́ rí, tabi o ti rí ìlẹ̀kùn òkùnkùn biribiri rí? Ṣé o mọ̀ bí ayé ti tóbi tó? Dá mi lóhùn, bí o bá mọ àwọn nǹkan wọnyi. “Níbo ni ọ̀nà ilé ìmọ́lẹ̀, ibo sì ni ibùgbé òkùnkùn, tí o óo fi lè mú un lọ sí ààyè rẹ̀, tí o fi lè mọ ọ̀nà tí ó lọ sí ilé rẹ̀? Dájúdájú o mọ̀, nítorí pé wọ́n ti bí ọ nígbà náà, o sá ti dàgbà! “Ṣé o ti wọ àwọn ilé ìkẹ́rùsí, tí mò ń kó yìnyín pamọ́ sí rí, tabi ibi tí mò ń kó òjò dídì sí, àní, àwọn tí mo ti pamọ́ de àkókò ìyọnu, fún ọjọ́ ogun ati ọjọ́ ìjà? Ṣé o mọ ibi tí ìmọ́lẹ̀ ti ń tàn wá, tabi ibi tí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn ti ń fẹ́ wá sórí ayé? “Ta ló lànà fún ọ̀wààrà òjò, ati fún ààrá, láti rọ òjò sí orí ilẹ̀ níbi tí kò sí eniyan, ati ní aṣálẹ̀, níbi tí kò sí ẹnikẹ́ni? Láti tẹ́ aṣálẹ̀ lọ́rùn, ati láti mú kí ilẹ̀ hu koríko? Ṣé òjò ní baba; àbí, baba wo ló sì bí ìrì? Ìyá wo ló bí yìnyín, inú ta ni òjò dídì sì ti jáde? Ó sọ omi odò di líle bí òkúta, ojú ibú sì dì bíi yìnyín. “Ṣé o lè fokùn so ìràwọ̀ Pileiadesi, tabi kí o tú okùn ìràwọ̀ Orioni? Ṣé o lè darí àkójọpọ̀ àwọn ìràwọ̀, ní àkókò wọn, tabi kí o ṣe atọ́nà ìràwọ̀ Beari ati àwọn ọmọ rẹ̀? Ṣé o mọ àwọn òfin tí ó de ojú ọ̀run? Tabi o lè fìdí wọn múlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé? “Ǹjẹ́ o lè pàṣẹ fún ìkùukùu pé, kí ó rọ òjò lé ọ lórí? Ṣé o lè pe mànàmáná pé kí ó wá kí o rán an níṣẹ́ kí ó wá bá ọ kí ó wí pé, ‘Èmi nìyí?’ Ta ló fi ọgbọ́n sinu ìkùukùu ati ìmọ̀ sinu ìrì? Ta ló lè fi ọgbọ́n ká ìkùukùu, tabi tí ó lè tú omi inú ìkùukùu dà sílẹ̀, nígbà tí ilẹ̀ bá gbẹ, tóbẹ́ẹ̀ tí ó dì, tí ó sì le koko? “Ṣé o lè wá oúnjẹ fún kinniun, tabi kí o fi oúnjẹ tẹ́ àwọn ọ̀dọ́ kinniun lọ́rùn, nígbà tí wọ́n bá dùbúlẹ̀ ninu ihò wọn, tabi tí wọ́n ba ní ibùba wọn? Ta ní ń wá oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ìwò, nígbà tí àwọn ọmọ wọn bá kígbe sí Ọlọrun, tí wọ́n sì ń káàkiri tí wọn ń wá oúnjẹ? “Ǹjẹ́ o mọ ìgbà tí àwọn ewúrẹ́ orí àpáta ń bímọ? Ṣé o ti ká àgbọ̀nrín mọ́ ibi tí ó ti ń bímọ rí? Ǹjẹ́ o lè ka iye oṣù tí wọ́n fi ń lóyún? Tabi o mọ ìgbà tí wọ́n bímọ? Ǹjẹ́ o mọ ìgbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀, tí wọ́n sì bímọ? Àwọn ọmọ wọn á di alágbára, wọn á dàgbà ninu pápá, wọn á sì lọ, láìpadà wá sọ́dọ̀ àwọn òbí wọn mọ́. “Ta ló fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́ lómìnira tí ó sì tú ìdè rẹ̀? Mo fi inú pápá ṣe ilé rẹ̀, ilẹ̀ oníyọ̀ sì di ibùgbé rẹ̀. Ó ń pẹ̀gàn ìdàrúdàpọ̀ inú ìlú ńlá, kò gbọ́ ariwo àwọn tí wọn ń fi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ṣiṣẹ́. Ó ń rìn káàkiri àwọn òkè bí ibùjẹ rẹ̀, ó sì ń wá ewéko tútù kiri. “Ṣé ẹfọ̀n ṣetán láti sìn ọ́? Ṣé yóo wá sùn ní ibùjẹ ẹran rẹ lálẹ́? Ṣé o lè so àjàgà mọ́ ọn lọ́rùn ní poro oko, tabi kí ó máa kọ ebè tẹ̀lé ọ? Ṣé o lè gbẹ́kẹ̀lé e nítorí pé agbára rẹ̀ pọ̀, tabi kí o fi iṣẹ́ rẹ sílẹ̀ fún un láti ṣe? Ṣé o ní igbagbọ pé yóo pada, ati pé yóo ru ọkà rẹ̀ wá sí ibi ìpakà rẹ? “Ògòǹgò lu ìyẹ́ rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ninu ọláńlá rẹ̀, ṣugbọn kò lè fò bí ẹyẹ àkọ̀? Ó yé ẹyin rẹ̀ sórí ilẹ̀, kí ooru ilẹ̀ lè mú wọn, ó gbàgbé pé ẹnìkan le tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ kí wọn sì fọ́, ati pé ẹranko ìgbẹ́ lè fọ́ wọn. Ògòǹgò kò náání àwọn ọmọ rẹ̀, ó ń ṣe sí wọn bí ẹni pé kì í ṣe òun ló bí wọn, kò bìkítà bí wahala rẹ̀ tilẹ̀ já sí asán; nítorí pé Ọlọrun kò fún un ní ọgbọ́n ati òye. Ṣugbọn nígbà tí ó bá ṣetán ati sáré, a máa fi ẹṣin ati ẹni tí ó gùn ún ṣe yẹ̀yẹ́. “Ṣé ìwọ ni o fún ẹṣin lágbára, tí o sì fi agbára ṣe gọ̀gọ̀ sí i lọ́rùn? Ṣé ìwọ lò ń mú kí ó máa ta pọ́nún bí eṣú, tí kíké rẹ̀ sì ń bani lẹ́rù? Ó fẹsẹ̀ walẹ̀ ní àfonífojì, ó yọ̀ ninu agbára rẹ̀, ó sì jáde lọ sí ojú ogun. Kò mọ ẹ̀rù, ọkàn rẹ̀ kì í rẹ̀wẹ̀sì, bẹ́ẹ̀ ni kì í sá fún idà. Ó gbé apó ọfà sẹ́yìn, tí ń mì pẹkẹpẹkẹ, pẹlu ọ̀kọ̀ tí ń kọ mànà, ati apata. Ó ń fi ẹnu họlẹ̀ pẹlu ìgboyà ati ìwàǹwára, nígbà tí ipè dún, ara rẹ̀ kò balẹ̀. Nígbà tí fèrè dún, ó kọ, ‘Hàáà!’ Ó ń gbóòórùn ogun lókèèrè, ó ń gbọ́ igbe ọ̀gágun tí ń pàṣẹ. “Ṣé ìwọ lo kọ́ àwòdì bí a ti í fò, tí ó fi na ìyẹ́ rẹ̀ sí ìhà gúsù? Ṣé ìwọ ni o pàṣẹ fún idì láti fò lọ sókè, tabi láti tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sórí òkè gíga? Ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí òkè gíga-gíga, ninu pàlàpálá àpáta. Níbẹ̀ ni ó ti ń ṣọ́ ohun tí yóo pa, ojú rẹ̀ a sì rí i láti òkèèrè réré. Àwọn ọmọ rẹ̀ a máa mu ẹ̀jẹ̀, ibi tí òkú bá sì wà ni idì máa ń wà.” OLUWA tún sọ fún Jobu pé, “Ṣé ẹni tí ń bá eniyan rojọ́ lè bá Olodumare rojọ́? Kí ẹni tí ń bá Ọlọrun jiyàn dáhùn.” Nígbà náà ni Jobu dá OLUWA lóhùn, ó ní: “OLUWA, kí ni mo jámọ́, tí n óo fi dá ọ lóhùn? Nítorí náà, mo ti dákẹ́ jẹ́ẹ́. Mo ti sọ̀rọ̀ ju bí ó ti yẹ lọ, n kò sì ní sọ̀rọ̀ mọ́.” Nígbà náà ni OLUWA tún bá Jobu sọ̀rọ̀ láti inú ìjì líle, ó ní, “Múra gírí bí ọkunrin, mo ní ìbéèrè láti bi ọ́, o óo sì dá mi lóhùn. Ṣé o fẹ́ sọ pé mò ń ṣe àìdára ni? O fẹ́ dá mi lẹ́bi kí á lè dá ọ láre? Ṣé o lágbára bí èmi Ọlọrun, àbí o lè sán wàá bí ààrá, nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, fi ọlá ati ìyìn ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́, kí o sì fi ògo ati ẹwà bo ara rẹ bí aṣọ. Fi ibinu rẹ hàn, wo gbogbo àwọn agbéraga, kí o sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀. Wo gbogbo àwọn agbéraga, kí o sì sọ wọ́n di yẹpẹrẹ, rún àwọn ẹni ibi mọ́lẹ̀ ní ipò wọn. Bo gbogbo wọn mọ́lẹ̀ papọ̀, dì wọ́n ní ìgbèkùn sí ipò òkú. Nígbà náà ni n óo gbà pé, agbára rẹ lè fún ọ ní ìṣẹ́gun. “Wo Behemoti, ẹran ńlá inú omi, tí mo dá gẹ́gẹ́ bí mo ti dá ọ, koríko ni ó ń jẹ bíi mààlúù! Wò ó bí ó ti lágbára tó! Ati irú okun tí awọ inú rẹ̀ ní. Ìrù rẹ̀ dúró ṣánṣán bí igi kedari, gbogbo iṣan itan rẹ̀ dì pọ̀. Egungun rẹ̀ dàbí ọ̀pá idẹ, ọwọ́ ati ẹsẹ̀ rẹ̀ rí bí irin. “Ó wà lára àwọn ohun àkọ́kọ́ tí èmi Ọlọrun dá, sibẹ ẹlẹ́dàá rẹ̀ nìkan ló lè pa á. Orí àwọn òkè ni ó ti ń rí oúnjẹ jẹ, níbi tí àwọn ẹranko ìgbẹ́ ti ń ṣeré. Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi lotusi, lábẹ́ ọ̀pá ìyè ninu ẹrẹ̀. Igi lotusi ni ó ń ṣíji bò ó, igi tí ó wà létí odò yí i ká. Kò náání ìgbì omi, kò bẹ̀rù bí odò Jọdani tilẹ̀ ru dé bèbè rẹ̀. Ṣé eniyan lè fi ìwọ̀ mú un? Tabi kí á fi ọ̀kọ̀ lu ihò sí imú rẹ̀? “Ṣé o lè fi ìwọ̀ fa Lefiatani jáde, tabi kí o fi okùn di ahọ́n rẹ̀? Ṣé o lè fi okùn sí imú rẹ̀, tabi kí o fi ìwọ̀ kọ́ ọ ní àgbọ̀n? Ṣé yóo bẹ̀ ọ́, tabi kí ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀? Ṣé yóo bá ọ dá majẹmu, pé kí o fi òun ṣe iranṣẹ títí lae? Ṣé o lè máa fi ṣeré bí ọmọ ẹyẹ, tabi kí o dè é lókùn fún àwọn iranṣẹbinrin rẹ? Ṣé àwọn oníṣòwò lè yọwó rẹ̀? Àbí wọ́n lè pín Lefiatani láàrin ara wọn? Ṣé o lè fi ọ̀kọ̀ gún ẹran ara rẹ̀, tabi kí o fi ẹ̀sín àwọn apẹja gún orí rẹ̀? Lọ fọwọ́ kàn án; kí o wo irú ìjà tí yóo bá ọ jà; o kò sì ní dán irú rẹ̀ wò mọ́ lae! “Ìrètí ẹni tí ó bá fẹ́ bá a jà yóo di òfo, nítorí ojora yóo mú un nígbà tí ó bá rí i. Ta ló láyà láti lọ jí i níbi tí ó bá sùn sí? Ta ló tó kò ó lójú? Ta ni mo gba nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀ tí mo níláti dá a pada fún un? Kò sí olúwarẹ̀ ní gbogbo ayé. “N kò ní yé sọ̀rọ̀ nípa ẹsẹ̀ rẹ̀, tabi nípa agbára rẹ̀ tabi dídára ìdúró rẹ̀. Ta ló tó bó awọ rẹ̀, tabi kí ó fi nǹkan gún igbá ẹ̀yìn rẹ̀? Ta ló tó ya ẹnu rẹ̀? Gbogbo eyín rẹ̀ ni ó kún fún ẹ̀rù. Ẹ̀yìn rẹ̀ kún fún ìpẹ́ tí ó dàbí apata, a tò wọ́n lẹ́sẹẹsẹ, wọ́n súnmọ́ ara wọn pẹ́kípẹ́kí bí èdìdì. Àwọn ìpẹ́ náà lẹ̀ mọ́ ara wọn tímọ́tímọ́, tóbẹ́ẹ̀ tí afẹ́fẹ́ kò lè fẹ́ kọjá láàrin wọn. Wọ́n so pọ̀, wọ́n lẹ̀ mọ́ ara wọn tóbẹ́ẹ̀, tí ohunkohun kò lè ṣí wọn. Bí ó bá sín, ìmọ́lẹ̀ á tàn jáde ní imú rẹ̀, ojú rẹ̀ ń tàn bíi ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ kutukutu. Ahọ́n iná ń yọ lẹ́nu rẹ̀ bí iná tí ń ta jáde, bẹ́ẹ̀ ni ahọ́n iná ń yọ lálá. Èéfín ń jáde ní imú rẹ̀, bíi ti ìkòkò gbígbóná ati ìgbẹ́ tí ń jó. Èémí tí ó ń mí jáde dàbí ògúnná, ahọ́n iná ń yọ ní ẹnu rẹ̀. Kìkì agbára ni ọrùn rẹ̀, ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ sì ń bẹ níwájú rẹ̀. Ìṣẹ́po ẹran ara rẹ̀ lẹ̀ pọ̀ mọ́ ara wọn, wọ́n lẹ̀ pọ̀, wọn kò sì ṣe é ṣí. Ọkàn rẹ̀ le bí òkúta, ó le ju ọlọ lọ. Bí ó bá dìde, ẹ̀rù á ba àwọn alágbára, wọn á bì sẹ́yìn, wọn á ṣubú lé ara wọn lórí. Bí idà tilẹ̀ bá a, kò ràn án, bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀kọ̀, ati ọfà, ati ẹ̀sín. Irin kò yàtọ̀ sí koríko lójú rẹ̀, idẹ sì dàbí igi tí ó ti rà. Bí wọn ta á lọ́fà, kò ní torí rẹ̀ sá, àwọn òkúta kànnàkànnà dàbí àgékù koríko lójú rẹ̀. Kùmọ̀ dàbí koríko lára rẹ̀, a sì máa fi ẹni tí ó ju ọ̀kọ̀ lù ú rẹ́rìn-ín. Ìpẹ́ ikùn rẹ̀ dàbí àpáàdì tí ó mú, wọn ń fa ilẹ̀ tútù ya bí ọkọ́. Ó mú kí ibú hó bí omi inú ìkòkò, ó ṣe òkun bí ìkòkò òróró ìpara. Bí ó bá ń rìn lọ, ipa ọ̀nà rẹ̀ a máa hàn lẹ́yìn rẹ̀, eniyan á rò pé òkun ń hó bí ọṣẹ ni. Kò sí ohun tí a lè fi wé láyé, ẹ̀dá tí ẹ̀rù kì í bà. Ó fojú tẹmbẹlu gbogbo ohun gíga, ó sì jọba lórí gbogbo àwọn ọmọ agbéraga.” Jobu bá dá OLUWA lóhùn ó ní: “Mo mọ̀ pé o lè ṣe ohun gbogbo, kò sì sí ohun tí ó lè da ìpinnu rẹ rú. Ta nìyí tí ń fi ìmọ̀ràn pamọ́ láìní òye? Àwọn ohun tí mo sọ kò yé mi, ìyanu ńlá ni wọ́n jẹ́ fún mi, n kò sì mọ̀ wọ́n. O ní kí n tẹ́tí sílẹ̀, nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀, kí n sì dáhùn nígbà tí o bá bèèrè nǹkan lọ́wọ́ mi. Ìró rẹ ni mo gbọ́ tẹ́lẹ̀, ṣugbọn nisinsinyii mo ti rí ọ; nítorí náà, ojú ara mi tì mí, fún ohun tí mo ti sọ, mo sì ronupiwada ninu erùpẹ̀ ati eérú.” Lẹ́yìn ìgbà tí OLUWA ti bá Jobu sọ̀rọ̀ tán, ó sọ fún Elifasi ará Temani pé, “Inú ń bí mi sí ìwọ ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ mejeeji. Nítorí ẹ kò sọ ohun tí ó tọ́ nípa mi, bí Jobu iranṣẹ mi ti ṣe. Nítorí náà, mú akọ mààlúù meje ati àgbò meje lọ sí ọ̀dọ̀ Jobu kí o rú ẹbọ sísun fún ara rẹ; Jobu iranṣẹ mi yóo sì gbadura fún ọ, n óo gbọ́ adura rẹ̀, n kò sì ní ṣe sí ọ gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ. Nítorí o kò sọ ohun tí ó tọ́ nípa mi gẹ́gẹ́ bí Jobu iranṣẹ mi ti ṣe.” Nítorí náà, Elifasi ará Temani, Bilidadi ará Ṣuha, ati Sofari ará Naama lọ ṣe ohun tí OLUWA sọ fún wọn, OLUWA sì gbọ́ adura Jobu. Lẹ́yìn ìgbà tí Jobu gbadura fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹtẹẹta tán, OLUWA dá ọrọ̀ Jobu pada, ó sì jẹ́ kí ó ní ìlọ́po meji àwọn ohun tí ó ti ní tẹ́lẹ̀. Àwọn arakunrin ati arabinrin Jobu ati àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ pada wá bẹ̀ ẹ́ wò. Wọ́n jẹ àsè ní ilé rẹ̀, wọ́n káàánú rẹ̀, wọ́n sì tù ú ninu, nítorí ohun burúkú tí OLUWA ti mú wá sórí rẹ̀, olukuluku wọn fún un ní owó ati òrùka wúrà kọ̀ọ̀kan. OLUWA bukun ìgbẹ̀yìn Jobu ju ti iṣaaju rẹ̀ lọ, ó ní ẹgbaaje (14,000) aguntan, ẹgbaata (6,000) ràkúnmí, ẹgbẹrun (1,000) àjàgà mààlúù ati ẹgbẹrun (1,000) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Ó tún bí ọmọkunrin meje ati ọmọbinrin mẹta. Ó pe àkọ́bí obinrin ni Jemima, ekeji ni Kesaya, ẹkẹta ni Kereni Hapuki. Kò sì sí ọmọbinrin tí ó lẹ́wà bí àwọn ọmọbinrin Jobu ní gbogbo ayé. Baba wọn sì fún wọn ní ogún láàrin àwọn arakunrin wọn. Lẹ́yìn náà Jobu tún gbé ogoje (140) ọdún sí i láyé, ó rí àwọn ọmọ ati àwọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ títí dé ìran kẹrin. Ó di arúgbó kùjọ́kùjọ́ kí ó tó kú. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni náà tí kò gba ìmọ̀ràn àwọn eniyan burúkú, tí kò bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ rìn, tí kò sì bá àwọn ẹlẹ́gàn kẹ́gbẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní ìfẹ́ sí òfin OLUWA, a sì máa ṣe àṣàrò lórí rẹ̀ tọ̀sán-tòru. Yóo dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń so ní àkókò tí ó yẹ, tí ewé rẹ̀ kì í rẹ̀. Gbogbo ohun tí ó bá dáwọ́lé níí máa yọrí sí rere. Àwọn eniyan burúkú kò rí bẹ́ẹ̀, ṣugbọn wọ́n dàbí fùlùfúlù tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ. Nítorí náà àwọn eniyan burúkú kò ní rí ìdáláre, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kò ní le wà ní àwùjọ àwọn olódodo. Nítorí OLUWA ń dáàbò bo àwọn olódodo, ṣugbọn àwọn eniyan burúkú yóo ṣègbé. Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń bínú fùfù tí àwọn eniyan ń gbìmọ̀ asán? Àwọn ọba ayé kó ara wọn jọ, àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n dojú kọ OLUWA ati àyànfẹ́ rẹ̀. Wọn ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á fa ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi dè wá já kí á sì yọ ara wa kúrò lóko ẹrú wọn.” Ẹni tí ó gúnwà lọ́run ń fi wọ́n rẹ́rìn-ín; OLUWA sì ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́. Lẹ́yìn náà, yóo sọ̀rọ̀ sí wọn ninu ibinu rẹ̀, yóo dẹ́rùbà wọ́n gidigidi ninu ìrúnú rẹ̀, Yóo wí pé, “Mo ti fi ọba mi jẹ, ní Sioni, lórí òkè mímọ́ mi.” N óo kéde ohun tí OLUWA pa láṣẹ ní ti èmi ọba; Ó wí fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi, lónìí ni mo bí ọ. Bèèrè lọ́wọ́ mi, èmi ó sì fún ọ ní àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo ayé yóo sì di tìrẹ. Ìwọ óo fi ọ̀pá irin fọ́ wọn, o óo sì fọ́ wọn túútúú bí ìkòkò amọ̀.” Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ kọ́gbọ́n; ẹ̀yin onídàájọ́ ayé, ẹ gba ìkìlọ̀. Ẹ fi ìbẹ̀rù sin OLUWA, ẹ yọ̀ pẹlu ìwárìrì. Ẹ júbà ọmọ náà, kí ó má baà bínú, kí ó má baà pa yín run lójijì; nítorí a máa yára bínú. Ayọ̀ ń bẹ fún gbogbo àwọn tí ó wá ààbò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. OLUWA, àwọn ọ̀tá mi pọ̀ pupọ! Ọ̀pọ̀ ni ó ń dìde sí mi! Ọpọlọpọ ni àwọn tí ń sọ kiri pé, Ọlọrun kò ní gbà mí sílẹ̀! Ṣugbọn ìwọ OLUWA ni ààbò mi, ògo mi, ati ẹni tí ó fún mi ní ìgboyà. Mo ké pe OLUWA, ó sì dá mi lóhùn láti òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Mo dùbúlẹ̀, mo sùn, mo sì jí, nítorí OLUWA ni ó ń gbé mi ró. Ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀tá tó yí mi ká kò le bà mí lẹ́rù. Dìde, OLUWA, gbà mí, Ọlọrun mi! Nítorí ìwọ ni o lu gbogbo àwọn ọ̀tá mi bolẹ̀, tí o sì ṣẹgun àwọn eniyan burúkú. OLUWA níí gbani, kí ibukun rẹ̀ kí ó wà lórí àwọn eniyan rẹ̀. Dá mi lóhùn nígbà tí mo bá pè ọ́, Ọlọrun mi olùdániláre. Ìwọ ni o yọ mí nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú, ṣàánú mi, kí o sì gbọ́ adura mi. Ẹ̀yin ọmọ eniyan, yóo ti pẹ́ tó, tí ẹ óo máa fi ojú ọlá mi gbolẹ̀, tí ẹ óo máa fẹ́ràn ọ̀rọ̀ asán, tí ẹ óo sì máa wá irọ́ kiri? Ṣugbọn kí ẹ mọ̀ dájú pé OLUWA ti ya olódodo sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀, OLUWA yóo gbọ́ nígbà tí mo bá pè é. Bí ó ti wù kí ẹ bínú tó, ẹ má dẹ́ṣẹ̀; ẹ bá ọkàn yín sọ̀rọ̀ lórí ibùsùn yín, kí ẹ sì dákẹ́ jẹ́ẹ́. Ẹ rú ẹbọ òdodo, kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA. Ọ̀pọ̀ eniyan ni ó ń bèèrè pé “Ta ni yóo ṣe wá ní oore?” OLUWA, tan ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ sí wa lára. Ìwọ ti fi ayọ̀ kún ọkàn mi ju ayọ̀ àwọn tí ó rí ọpọlọpọ ọkà ati ọtí waini nígbà ìkórè. N óo dùbúlẹ̀, n óo sì sùn ní alaafia, nítorí ìwọ OLUWA nìkan ni o mú mi wà láìléwu. Fetí sí ọ̀rọ̀ mi, OLUWA; kíyèsí ìmí ẹ̀dùn mi. Fetí sí igbe mi, Ọba mi ati Ọlọrun mi, nítorí ìwọ ni mò ń gbadura sí. OLUWA, o óo gbọ́ ohùn mi ní òwúrọ̀, ní òwúrọ̀ ni n óo máa sọ ẹ̀dùn ọkàn mi fún ọ; èmi óo sì máa ṣọ́nà. Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọrun tí inú rẹ̀ dùn sí ìwà burúkú; àwọn ẹni ibi kò sì lè bá ọ gbé. Àwọn tí ń fọ́nnu kò lè dúró níwájú rẹ; o kórìíra gbogbo àwọn aṣebi. O máa ń pa àwọn òpùrọ́ run; OLUWA, o kórìíra àwọn apani ati ẹlẹ́tàn. Ṣugbọn nípa ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, èmi óo wọ inú ilé rẹ; n óo fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ wólẹ̀, n óo sì kọjúsí tẹmpili mímọ́ rẹ. OLUWA, tọ́ mi sọ́nà òdodo rẹ, nítorí àwọn ọ̀tá mi; jẹ́ kí ọ̀nà rẹ hàn kedere níwájú mi. Nítorí kò sí òtítọ́ kan lẹ́nu wọn; ìparun ni ó wà ninu ọkàn wọn. Isà òkú tí ó yanu sílẹ̀ ni ọ̀fun wọn; ẹnu wọn kún fún ìpọ́nni ẹ̀tàn. Dá wọn lẹ́bi, Ọlọrun, kí o sì fìyà jẹ wọ́n; jẹ́ kí ìgbìmọ̀pọ̀ wọn ó gbé wọn ṣubú. Ta wọ́n nù nítorí ọ̀pọ̀ ìrékọjá wọn, nítorí pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ọ. Ṣugbọn jẹ́ kí inú gbogbo àwọn tí ó sá di ọ́ ó dùn, kí wọn ó máa kọrin ayọ̀ títí lae. Dáàbò bò wọ́n, kí àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ sì máa yọ̀ ninu rẹ. Nítorí ìwọ OLUWA a máa bukun àwọn olódodo; ò sì máa fi ojurere rẹ tí ó dàbí apata dáàbò bò wọ́n. OLUWA, má fi ibinu bá mi wí; má sì fi ìrúnú jẹ mí níyà. Ṣàánú mi, OLUWA, nítorí àárẹ̀ mú ọkàn mi, OLUWA, wò mí sàn nítorí ara ń ni mí dé egungun. Ọkàn mi kò balẹ̀ rárá, yóo ti pẹ́ tó, OLUWA, yóo ti pẹ́ tó? OLUWA, pada wá gbà mí, gbà mí là nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀. Nítorí kò sí ẹni tí yóo ranti rẹ lẹ́yìn tí ó bá ti kú. Àbí, ta ló lè yìn ọ́ ninu isà òkú? Ìkérora dá mi lágara: ní òròòru ni mò ń fi omijé rẹ ẹní mi; tí mò ń sunkún tí gbogbo ibùsùn mi ń tutù. Ìbànújẹ́ sọ ojú mi di bàìbàì, agbára káká ni mo fi lè ríran nítorí ìnilára àwọn ọ̀tá. Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin oníṣẹ́ ibi, nítorí OLUWA ti gbọ́ ìró ẹkún mi. OLUWA ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi, OLUWA ti tẹ́wọ́gba adura mi. Ojú yóo ti gbogbo àwọn ọ̀tá mi; ìdààmú ńlá yóo bá wọn, wọn óo sá pada, ojú yóo sì tì wọ́n lójijì. OLUWA, Ọlọrun mi, ìwọ ni mo sá di; gbà mí là, kí o sì yọ mí lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi. Kí wọn má baà fà mí ya bíi kinniun, kí wọn máa wọ́ mi lọ láìsí ẹni tí ó lè gbà mí sílẹ̀. OLUWA, Ọlọrun mi, bí mo bá ṣe nǹkan yìí, bí iṣẹ́ ibi bá ń bẹ lọ́wọ́ mi, bí mo bá fi ibi san án fún olóore, tabi tí mo bá kó ọ̀tá mi lẹ́rú láìnídìí, jẹ́ kí ọ̀tá ó lé mi bá, kí ó tẹ̀ mí pa, kí ó sì bo òkú mi mọ́ ilẹ̀ẹ́lẹ̀. OLUWA, fi ibinu dìde! Gbéra, kí o bá àwọn ọ̀tá mi jà ninu ìrúnú wọn; jí gìrì, Ọlọrun mi; ìwọ ni o ti fi ìlànà òdodo lélẹ̀. Jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè ayé ó rọ̀gbà yí ọ ká, kí o sì máa jọba lé wọn lórí láti òkè wá. OLUWA ló ń ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ayé; dá mi láre, OLUWA, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi ati ìwà pípé mi. Ìwọ Ọlọrun Olódodo, tí o mọ èrò ati ìfẹ́ inú eniyan, fi òpin sí ìwà ibi àwọn eniyan burúkú, kí o sì fi ìdí àwọn olódodo múlẹ̀. Ọlọrun ni aláàbò mi, òun níí gba àwọn ọlọ́kàn mímọ́ là. Onídàájọ́ òdodo ni Ọlọrun, a sì máa bínú sí àwọn aṣebi lojoojumọ. Bí wọn kò bá yipada, Ọlọrun yóo pọ́n idà rẹ̀; ó ti tẹ ọrun rẹ̀, ó sì ti fi ọfà lé e. Ó ti pèsè ohun ìjà ikú sílẹ̀, ó sì ti tọ́jú ọfà iná. Wò ó, eniyan burúkú lóyún ibi, ó lóyún ìkà, ó sì bí èké. Ó gbẹ́ kòtò, ó sì jìn sinu kòtò tí ó gbẹ́. Ìkà rẹ̀ pada sórí ara rẹ̀, àní ìwà ipá rẹ̀ sì já lù ú ní àtàrí. N óo fi ọpẹ́ tí ó yẹ fún OLUWA nítorí òdodo rẹ̀, n óo fi orin ìyìn kí OLUWA, Ọ̀gá Ògo. OLUWA, Oluwa wa, orúkọ rẹ níyìn pupọ ní gbogbo ayé! Ìwọ ni o gbé ògo rẹ kalẹ̀ lókè ọ̀run. Àwọn ọmọ-ọwọ́ ati àwọn ọmọ-ọmú ń kọrin ògo rẹ, wọ́n ti fi ìdí agbára rẹ múlẹ̀, nítorí àwọn tí ó kórìíra rẹ, kí á lè pa àwọn ọ̀tá ati olùgbẹ̀san lẹ́nu mọ́. Nígbà tí mo ṣe akiyesi ojú ọ̀run, iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀, tí o sọlọ́jọ̀— Kí ni eniyan jẹ́, tí o fi n náání rẹ̀? Àní, kí ni ọmọ eniyan, tí o fi ń ṣìkẹ́ rẹ̀? O dá a, ipò rẹ̀ rẹlẹ̀ díẹ̀ sí ti ìwọ Ọlọrun, o sì ti fi ògo ati ọlá dé e ní adé. O mú un jọba lórí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, o sì fi gbogbo nǹkan sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀: àwọn aguntan, ati àwọn mààlúù, ati gbogbo ẹranko ninu igbó; àwọn ẹyẹ ojú ọrun, àwọn ẹja inú òkun, ati gbogbo nǹkan tí ó ń lúwẹ̀ẹ́ ninu òkun. OLUWA, Oluwa wa, orúkọ rẹ níyìn pupọ ní gbogbo ayé! OLUWA, tọkàntọkàn ni n óo fi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ; n óo ròyìn gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ. N óo yọ̀, inú mi yóo sì máa dùn nítorí rẹ; n óo kọ orin ìyìn orúkọ rẹ, ìwọ Ọ̀gá-Ògo jùlọ. Nígbà tí àwọn ọ̀tá mi pẹ̀yìndà, wọ́n ṣubú, wọ́n sì parun níwájú rẹ. Nítorí ìwọ ni o fi ìdí ẹ̀tọ́ mi múlẹ̀, tí o sì dá mi láre; ìwọ ni o jókòó lórí ìtẹ́, o sì ṣe ìdájọ́ òdodo. O bá àwọn orílẹ̀-èdè wí, o pa àwọn eniyan burúkú run, o sì pa orúkọ wọn rẹ́ títí lae. O pa àwọn ọ̀tá run patapata, o sọ ìlú wọn di ahoro, o sì sọ wọ́n di ẹni ìgbàgbé. Ṣugbọn OLUWA gúnwà títí lae, ó ti fi ìdí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀ múlẹ̀. Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé, yóo sì fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè. OLUWA ni ààbò fún àwọn tí a ni lára, òun ni ibi ìsádi ní ìgbà ìpọ́njú. Àwọn tí ó mọ̀ ọ́ yóo gbẹ́kẹ̀lé ọ; nítorí ìwọ, OLUWA, kìí kọ àwọn tí ń wá ọ sílẹ̀. Ẹ kọrin ìyìn sí OLUWA, tí ó gúnwà ní Sioni! Ẹ kéde iṣẹ́ rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè! Nítorí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ranti, kò sì gbàgbé igbe ẹkún àwọn tí a pọ́n lójú. OLUWA, ṣàánú fún mi! Wò ó bí àwọn ọ̀tá mi ṣe ń pọ́n mi lójú. Gbà mí kúrò létí bèbè ikú, kí n lè kọrin ìyìn rẹ, kí n sì lè yọ ayọ̀ ìgbàlà rẹ lẹ́nu ibodè Sioni. Àwọn orílẹ̀-èdè ti jìn sinu kòtò tí wọ́n gbẹ́, wọ́n sì ti kó sinu àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀. OLUWA ti fi ara rẹ̀ hàn, ó ti ṣe ìdájọ́, àwọn eniyan burúkú sì ti kó sinu tàkúté ara wọn. Àwọn eniyan burúkú, àní, gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó gbàgbé Ọlọrun, ni yóo lọ sinu isà òkú. Nítorí pé OLUWA kò ní fi ìgbà gbogbo gbàgbé àwọn aláìní, bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn talaka kò ní já sí òfo títí lae. Dìde, OLUWA, má jẹ́ kí eniyan ó borí, jẹ́ kí á ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè níwájú rẹ. OLUWA, da ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ bò wọ́n, jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ̀ pé aláìlágbára eniyan ni àwọn. Kí ló dé tí o fi jìnnà réré, OLUWA, tí o sì fara pamọ́ ní ìgbà ìpọ́njú? Pẹlu ìgbéraga ni eniyan burúkú fi ń dọdẹ àwọn aláìní; jẹ́ kí ó bọ́ sinu tàkúté tí ó fi àrékérekè dẹ. Eniyan burúkú ń fọ́nnu lórí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀, Ó ń bu ọlá fún wọ̀bìà, ó sì ń kẹ́gàn OLUWA. Eniyan burúkú kò wá Ọlọrun, nítorí ìgbéraga ọkàn rẹ̀, kò tilẹ̀ sí ààyè fún Ọlọrun ninu gbogbo ìrònú rẹ̀. Nígbà gbogbo ni nǹkan ń dára fún un. Ìdájọ́ rẹ, Ọlọrun, ga pupọ, ó ju òye rẹ̀ lọ; ó ń yọ ṣùtì ètè sí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ó ń rò lọ́kàn ara rẹ̀ pé, kò sí ohun tí ó lè bi òun ṣubú, ati pé ní gbogbo ọjọ́ ayé òun, òun kò ní ní ìṣòro. Ẹnu rẹ̀ kún fún èpè, ẹ̀tàn ati ìhàlẹ̀; ìjàngbọ̀n ati ọ̀rọ̀ ibi sì wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀. Ó ń lúgọ káàkiri létí abúlé, níbi tó fara pamọ́ sí ni ó ti ń pa àwọn aláìṣẹ̀; ó ń fojú ṣọ́ àwọn aláìṣẹ̀ tí yóo pa. Ó fara pamọ́ bíi kinniun tí ó wà ní ibùba; ó fara pamọ́ láti ki aláìní mọ́lẹ̀; ó mú aláìní, ó sì fi àwọ̀n fà á lọ. Ó wó aláìṣẹ̀ mọ́lẹ̀, ó tẹ orí wọn ba, ó sì fi agbára bì wọ́n ṣubú. Ó sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé, “Ọlọrun ti gbàgbé, OLUWA ti gbé ojú kúrò, kò sì ní rí i laelae.” Dìde, OLUWA; Ọlọrun, wá nǹkankan ṣe sí i; má sì gbàgbé àwọn tí a nilára. Kí ló dé tí eniyan burúkú fi ń kẹ́gàn Ọlọrun, tí ó ń sọ lọ́kàn rẹ̀ pé, “Ọlọrun kò ní bi mí?” Ṣugbọn ìwọ Ọlọrun rí gbogbo nǹkan, nítòótọ́, o kíyèsí ìṣòro ati ìyà, kí o baà lè fi ọwọ́ ara rẹ gbẹ̀san; nítorí ìwọ ni àwọn aláìṣẹ̀ gbẹ́kẹ̀lé, ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìníbaba. Ṣẹ́ eniyan burúkú ati aṣebi lápá, tú àṣírí gbogbo ìwà burúkú rẹ̀, má sì jẹ́ kí ọ̀kan ninu wọn farasin. OLUWA ni ọba lae ati laelae. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo pòórá lórí ilẹ̀ rẹ. OLUWA, o óo gbọ́ igbe àwọn tí a nilára; o óo mú wọn lọ́kàn le, o óo sì dẹ etí sílẹ̀ sí igbe wọn kí o lè ṣe ẹ̀tọ́ fún àwọn aláìníbaba ati àwọn ẹni tí à ń pọ́n lójú, kí ọmọ eniyan, erùpẹ̀ lásánlàsàn, má lè dẹ́rù bani mọ́. OLUWA ni mo sá di; ẹ ṣe lè wí fún mi pé, “Fò lọ sórí òkè bí ẹyẹ; ẹ wo àwọn eniyan burúkú bí wọ́n ti kẹ́ ọfà; wọ́n fa ọrun; wọ́n sì fi òkùnkùn bojú láti ta olódodo lọ́fà. Nígbà tí ìpìlẹ̀ bá bàjẹ́, kí ni olódodo lè ṣe?” OLUWA ń bẹ ninu tẹmpili mímọ́ rẹ̀, ìtẹ́ rẹ̀ wà lọ́run; OLUWA ń kíyèsí àwọn ọmọ eniyan, ó sì ń yẹ̀ wọ́n wò. OLUWA ń yẹ àwọn olódodo, ati eniyan burúkú wò, ṣugbọn tọkàntọkàn ni ó kórìíra àwọn tí ó fẹ́ràn ìwà ipá. Yóo rọ̀jò ẹ̀yinná ati imí ọjọ́ gbígbóná sórí àwọn eniyan burúkú; ìjì gbígbóná ni yóo sì jẹ́ ìpín wọn. Nítorí olódodo ni OLUWA, ó sì fẹ́ràn òdodo; àwọn olóòótọ́ ni yóo rí ojú rẹ̀. Gbani, OLUWA; nítorí àwọn olódodo kò sí mọ́; àwọn olóòótọ́ ti pòórá láàrin àwọn ọmọ eniyan. Olukuluku ń purọ́ fún ẹnìkejì rẹ̀; ọ̀rọ̀ ìpọ́nni èké ati ẹ̀tàn ni wọ́n ń bá ara wọn sọ. Kí OLUWA pa gbogbo àwọn tí ń fi èké pọ́nni run, ati àwọn tí ń fọ́nnu, àwọn tí ń wí pé, “Ẹnu wa yìí ni a óo fi ṣẹgun, àwa la ni ẹnu wa; ta ni ó lè mú wa?” OLUWA wí pé, “Nítorí ìnira àwọn aláìṣẹ̀, ati nítorí ìkérora àwọn tí à ń pọ́n lójú, n óo dìde nisinsinyii, n óo sì dáàbò bò wọ́n bí ọkàn wọn ti ń fẹ́.” Ìlérí tó dájú ni ìlérí OLUWA, ó dàbí fadaka tí a yọ́ ninu iná ìléru amọ̀, tí a dà ninu iná nígbà meje. Dáàbò bò wá, OLUWA, pa wá mọ́ laelae kúrò lọ́wọ́ irú àwọn eniyan báwọ̀nyí. Àwọn eniyan burúkú ń yan kiri, níwọ̀n ìgbà tí àwọn eniyan ń ṣe àpọ́nlé iṣẹ́ ibi. Yóo ti pẹ́ tó, OLUWA? Ṣé o óo wá gbàgbé mi laelae ni? Títí di ìgbà wo ni o óo fi ojú pamọ́ fún mi? Títí di ìgbà wo ni ọkàn mi yóo gbọgbẹ́ tí ìbànújẹ́ yóo gba ọkàn mi kan, ní gbogbo ìgbà? Títí di ìgbà wo ni àwọn ọ̀tá mi yóo máa yọ̀ mí? Bojúwò mí, kí o sì dá mi lóhùn, OLUWA, Ọlọrun mi. Tan ìmọ́lẹ̀ sí ojú mi, kí n má baà sun oorun ikú. Kí ọ̀tá mi má baà wí pé, “Mo ti rẹ́yìn rẹ̀.” Kí àwọn tí ó kórìíra mi má baà yọ̀ bí mo bá ṣubú. Ṣùgbọ́n èmi gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀; n óo máa yọ̀ nítorí pé o óo gbà mí. N óo máa kọrin sí ọ, OLUWA, nítorí o ṣeun fún mi lọpọlọpọ. Òmùgọ̀ sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé, “Ọlọrun kò sí.” Wọ́n bàjẹ́, ohun ìríra ni iṣẹ́ ọwọ́ wọn, kò sì sí ẹnìkan ninu wọn tí ń ṣe rere. OLUWA bojú wo ilẹ̀, láti ọ̀run wá, ó wo àwọn ọmọ eniyan, láti mọ̀ bí àwọn kan bá wà tí wọ́n gbọ́n, tí wọn ń wá Ọlọrun. Gbogbo wọn ti ṣìnà, gbogbo wọn pátá ni wọ́n sì ti bàjẹ́; kò sí ẹnìkan tí ń ṣe rere, kò sí ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo. Ṣé gbogbo àwọn aṣebi kò gbọ́n ni? Àwọn tí ń jẹ eniyan mi bí ẹni jẹun, àwọn tí kì í ké pe OLUWA. Níbẹ̀ ni a óo ti dẹ́rù bà wọ́n gidigidi, nítorí Ọlọrun ń bẹ pẹlu àwọn olódodo. Ẹ̀yin ń fẹ́ da ètò aláìní rú, ṣugbọn OLUWA ni ààbò rẹ̀. Ìbá ti dára tó kí ìgbàlà Israẹli ti Sioni wá! Nígbà tí OLUWA bá dá ire àwọn eniyan rẹ̀ pada, Jakọbu yóo yọ̀, inú Israẹli yóo sì dùn. OLUWA, ta ni ó lè máa gbé inú àgọ́ rẹ? Ta ni ó lè máa gbé orí òkè mímọ́ rẹ? Ẹni tí ń rìn déédéé, tí ń ṣe òdodo; tí sì ń fi tọkàntọkàn sọ òtítọ́. Ẹni tí kò fi ahọ́n rẹ̀ sọ̀rọ̀ eniyan lẹ́yìn, tí kò ṣe ibi sí ẹnìkejì rẹ̀, tí kò sì sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn nípa aládùúgbò rẹ̀. Ẹni tí kò ka ẹni ẹ̀kọ̀ sí, ṣugbọn a máa bu ọlá fún àwọn tí ó bẹ̀rù OLUWA; bí ó bá jẹ́ ẹ̀jẹ́, kì í yẹ̀ ẹ́; bí ẹ̀jẹ́ tí ó ti wù kí ó nira tó. Kì í yáni lówó kí ó gba èlé, kìí sìí gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ aláìṣẹ̀. Ẹni tí ó bá ṣe nǹkan wọnyi, ẹsẹ̀ rẹ̀ kò ní yẹ̀ laelae. Pa mí mọ́ Ọlọrun, nítorí ìwọ ni mo sá di. Mo wí fún ọ, OLUWA, pé, “Ìwọ ni Oluwa mi; ìwọ nìkan ni orísun ire mi.” Nípa àwọn eniyan mímọ́ tí ó wà nílẹ̀ yìí, wọ́n jẹ́ ọlọ́lá tí àwọn eniyan fẹ́ràn. “Ìbànújẹ́ àwọn tí ń sá tọ ọlọrun mìíràn lẹ́yìn yóo pọ̀: Èmi kò ní bá wọn ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ fún ìrúbọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kò ní gbọ́ orúkọ wọn lẹ́nu mi.” OLUWA, ìwọ ni ìpín mi, ìwọ ni mo yàn; ìwọ ni ò ń jẹ́ kí ọ̀ràn mi fìdí múlẹ̀. Ìpín tí ó bọ́ sí mi lọ́wọ́ dára pupọ; ogún rere ni ogún ti mo jẹ. Èmi óo máa yin OLUWA, ẹni tí ó ń fún mi ní òye; ọkàn mi ó sì máa tọ́ mi sọ́nà ní òròòru. Mò ń wo OLUWA ní iwájú mi nígbà gbogbo, nítorí pé Ọlọrun dúró tì mí, ẹsẹ̀ mi kò ní yẹ̀. Nítorí náà ni ọkàn mi ṣe ń yọ̀, tí inú mi dùn; ara sì rọ̀ mí. Nítorí o kò ní gbàgbé mi sí ipò òkú, bẹ́ẹ̀ ni o kò ní jẹ́ kí ẹni tí ó fi tọkàntọkàn sìn ọ́ rí ìdíbàjẹ́. O ti fi ọ̀nà ìyè hàn mí; ayọ̀ kíkún ń bẹ ní iwájú rẹ, ìgbádùn àìlópin sì ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ. Gbọ́ tèmi OLUWA, àre ni ẹjọ́ mi; fi ìtara gbọ́ igbe mi. Fetí sí adura mi nítorí kò sí ẹ̀tàn ní ẹnu mi. Jẹ́ kí ìdáláre mi ti ọ̀dọ̀ rẹ wá; kí o sì rí i pé ẹjọ́ mi tọ́. Yẹ ọkàn mi wò; bẹ̀ mí wò lóru. Dán mi wò, o kò ní rí ohun burúkú kan; n kò ní fi ẹnu mi dẹ́ṣẹ̀. Nítorí ohun tí o wí nípa èrè iṣẹ́ ọwọ́ eniyan, mo ti yàgò fún àwọn oníwà ipá. Mò ń tọ ọ̀nà rẹ tààrà; ẹsẹ̀ mi kò sì yọ̀. Mo ké pè ọ́, dájúdájú ìwọ Ọlọrun yóo dá mi lóhùn, dẹ etí rẹ sí mi, kí o sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn lọ́nà ìyanu, fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gba àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ kúrò lọ́wọ́ àwọn tí ó gbógun tì wọ́n. Pa mí mọ́ bí ẹyin ojú, dáàbò bò mí lábẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ; lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú tí ó gbé ìjà kò mí, àní lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá apani tí ó yí mi ká. Ojú àánú wọn ti fọ́, ọ̀rọ̀ ìgbéraga sì ń ti ẹnu wọn jáde. Wọn ń lépa mi; wọ́n sì ti yí mi ká báyìí; wọn ń ṣọ́ bí wọn ó ṣe bì mí ṣubú. Wọ́n dàbí kinniun tí ó ṣetán láti pa ẹran jẹ, àní bí ọmọ kinniun tí ó ba ní ibùba. Dìde, OLUWA! Dojú kọ wọ́n; là wọ́n mọ́lẹ̀; fi idà rẹ gbà mí lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú. OLUWA, fi ọwọ́ ara rẹ gbà mí lọ́wọ́ àwọn eniyan wọnyi; àwọn tí ìpín wọn jẹ́ ohun ti ayé yìí, fi ohun rere jíǹkí àwọn ẹni tí o pamọ́; jẹ́ kí àwọn ọmọ jẹ àjẹyó; sì jẹ́ kí àwọn ọmọ ọmọ wọn rí ogún wọn jẹ. Ní tèmi, èmi óo rí ojú rẹ nítorí òdodo mi, ìrísí rẹ yóo sì tẹ́ mi lọ́rùn nígbà tí mo bá jí. Mo fẹ́ràn rẹ, OLUWA, agbára mi. OLUWA ni àpáta mi, ibi ààbò mi, ati olùgbàlà mi; Ọlọrun mi, àpáta mi, ninu ẹni tí ààbò mi wà. Òun ni asà mi, ìwo ìgbàlà mi ati ibi ìsásí mi. Mo ké pe OLUWA, ẹni tí ìyìn yẹ, ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi. Ikú wé mọ́ mi bí okùn, ìparun sì bò mí mọ́lẹ̀ bíi rírú omi. Isà òkú yí mi ká, tàkúté ikú sì dojú kọ mí. Ninu ìpọ́njú mi mo ké pe OLUWA, Ọlọrun mi ni mo ké pè. Ó gbọ́ ohùn mi láti inú ilé mímọ́ rẹ̀, ó sì tẹ́tí sí igbe mi. Ilẹ̀ ayé wárìrì, ó sì mì tìtì, ìpìlẹ̀ àwọn òkè mì jìgìjìgì; wọ́n wárìrì nítorí tí ó bínú. Èéfín ṣẹ́ jáde láti ihò imú rẹ̀, iná ajónirun yọ jáde láti ẹnu rẹ̀; ẹ̀yinná sì ń jò bùlà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá. Ó dẹ ojú ọ̀run sílẹ̀, ó sì sọ̀kalẹ̀ wá, ìkùukùu tó ṣókùnkùn biribiri sì wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó gun orí Kerubu, ó sì fò, ó fò lọ sókè lórí ìyẹ́ apá afẹ́fẹ́. Ó fi òkùnkùn bora bí aṣọ, ìkùukùu tí ó ṣókùnkùn, tí ó sì kún fún omi ni ó fi ṣe ìbòrí. Ninu ìmọ́lẹ̀ níwájú rẹ, ẹ̀yinná ati yìnyín ń fọ́n jáde, láti inú ìkùukùu. OLUWA sán ààrá láti ọ̀run, Ọ̀gá Ògo fọhùn, òjò dídì ati ẹ̀yinná sì fọ́n jáde. Ó ta ọfà rẹ̀ jáde, ó sì fọ́n wọn ká, ó jẹ́ kí mànàmáná kọ, ó sì tú wọn ká. Nígbà náà ni ìsàlẹ̀ òkun hàn ketekete, ìpìlẹ̀ ayé sì fojú hàn gbangba nítorí ìbáwí rẹ, OLUWA, ati nítorí agbára èémí ihò imú rẹ. Ó nawọ́ láti òkè wá, ó sì dì mí mú, ó fà mí jáde láti inú ibú omi. Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi tí ó lágbára, ati lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi; nítorí wọ́n lágbára jù mí lọ. Wọ́n gbógun tì mí ní ọjọ́ ìpọ́njú mi, ṣugbọn OLUWA ni aláfẹ̀yìntì mi. Ó mú mi jáde wá síbi tí ó láàyè, ó yọ mí jáde nítorí tí inú rẹ̀ dùn sí mi. OLUWA ti san án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi, bí ọwọ́ mi ṣe mọ́ ni ó ṣe pín mi lérè. Nítorí tí mo ti pa ọ̀nà OLUWA mọ́, n kò ṣe ibi nípa yíyà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun mi. Nítorí pé gbogbo òfin rẹ̀ ni mo tẹ̀lé, n kò sì yà kúrò ninu ìlànà rẹ̀. Mo wà ní àìlẹ́bi níwájú rẹ̀, mo sì ti yẹra fún ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí náà ni OLUWA ṣe san án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi; ati gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ mi ṣe mọ́ lójú rẹ̀. Ò máa dúró ti àwọn tí ó dúró tì ọ́, ò sì máa ṣe àṣepé fún àwọn tí ó pé; mímọ́ ni ọ́ sí àwọn tí ọkàn wọn mọ́, ṣugbọn àwọn alárèékérekè ni o fi ọgbọ́n tayọ. Nítorí tí o máa ń gba àwọn onírẹ̀lẹ̀ là, ṣugbọn o máa ń rẹ àwọn onigbeeraga sílẹ̀. Nítorí ìwọ ni o mú kí àtùpà mi máa tàn, OLUWA, Ọlọrun mi ni ó tan ìmọ́lẹ̀ sí òkùnkùn mi. Pẹlu ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, mo lè run ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun, àní, pẹlu àtìlẹ́yìn Ọlọrun mi, mo lè fo odi ìlú. Ní ti Ọlọrun, ọ̀nà rẹ̀ pé, pípé ni ọ̀rọ̀ OLUWA; òun sì ni ààbò fún gbogbo àwọn tí ó sá di í. Ta tún ni Ọlọrun, bíkòṣe OLUWA? Àbí, ta ni àpáta, àfi Ọlọrun wa? Ọlọrun tí ó gbé agbára wọ̀ mí, tí ó sì mú ọ̀nà mi pé. Ó fi eré sí mi lẹ́sẹ̀ bíi ti àgbọ̀nrín, ó sì fún mi ní ààbò ní ibi ìsásí. Ó kọ́ mi ní ogun jíjà tóbẹ́ẹ̀ tí mo fi lè fa ọrun idẹ. O ti fún mi ní asà ìgbàlà rẹ, ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ó gbé mi ró, ìrànlọ́wọ́ rẹ sì ni ó sọ mí di ẹni ńlá. O la ọ̀nà tí ó gbòòrò fún mi, n kò sì fi ẹsẹ̀ rọ́. Mo lé àwọn ọ̀tá mi, ọwọ́ mi sì tẹ̀ wọ́n, n kò bojú wẹ̀yìn títí a fi pa wọ́n run. Mo ṣá wọn lọ́gbẹ́, wọn kò lè dìde, wọ́n ṣubú sí abẹ́ ẹsẹ̀ mi. O gbé agbára ogun wọ̀ mí; o sì mú àwọn tí ó dìde sí mi wólẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ mi. O mú kí àwọn ọ̀tá mi máa sá níwájú mi, mo sì pa àwọn tí ó kórìíra mi run. Wọ́n kígbe pé, “Ẹ gbà wá o!” Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó gbà wọ́n, wọ́n ké pe OLUWA, ṣugbọn kò dá wọn lóhùn. Mo lọ̀ wọ́n lúbúlúbú bí eruku tí afẹ́fẹ́ ń gbá lọ, mo dà wọ́n nù bí ẹni da omi ẹrẹ̀ nù. O gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tẹ̀ àwọn eniyan, o fi mí ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè; àwọn orílẹ̀-èdè tí n kò mọ̀ rí sì ń sìn mí. Bí wọ́n bá ti gbúròó mi ni wọ́n ń gbọ́ràn sí mi lẹ́nu; àwọn àjèjì ń fi ìbẹ̀rùbojo tẹríba, wọ́n ń wá ojurere mi. Àyà pá àwọn àlejò, wọ́n sì fi ìbẹ̀rùbojo sá jáde kúrò ní ibi tí wọ́n sápamọ́ sí. OLUWA wà láàyè! Ẹni ìyìn ni àpáta mi! Ẹni àgbéga ni Ọlọrun ìgbàlà mi! Ọlọrun tí ó ń gbẹ̀san fún mi, tí ó sì ń tẹ orí àwọn eniyan ba fún mi; Ọlọrun tí ó gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi; tí ó sì gbé mi ga ju àwọn abínú-ẹni lọ; ìwọ ni o gbà mí lọ́wọ́ àwọn ẹni ipá tí ó dìde sí mi. Nítorí náà ni èmi ó ṣe máa yìn ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, OLUWA, èmi ó sì máa kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ. Ó fi ìṣẹ́gun ńlá fún ọba rẹ̀, ó sì fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ han ẹni àmì òróró rẹ̀, àní Dafidi ati ìrandíran rẹ̀ títí lae. Ojú ọ̀run ń sọ̀rọ̀ ògo Ọlọrun, òfuurufú sì ń kéde iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Ọjọ́ dé ọjọ́ ń sọ ọ́ ní àsọgbà òru dé òru sì ń fi ìmọ̀ rẹ̀ hàn. Wọn kò fọ èdè kankan, wọn kò sì sọ ọ̀rọ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọ́ ohùn wọn; sibẹ ìró wọn la gbogbo ayé já, ọ̀rọ̀ wọn sì dé òpin ayé. Ó pàgọ́ fún oòrùn lójú ọ̀run, tí ó ń yọ jáde bí ọkọ iyawo tí ń jáde láti inú yàrá rẹ̀, ati bí akọni tí ara ń wá láti fi tayọ̀tayọ̀ sáré ìje. Láti apá kan ojú ọ̀run ni ó ti ń yọ wá, a máa yípo gbogbo ojú ọ̀run dé apá keji; kò sì sí ohun tí ó bọ́ lọ́wọ́ ooru rẹ̀. Òfin OLUWA pé, a máa sọ ọkàn jí; àṣẹ OLUWA dájú, ó ń sọ òpè di ọlọ́gbọ́n. Ìlànà OLUWA tọ́, ó ń mú ọkàn yọ̀, àṣẹ OLUWA péye, a máa lani lójú. Ìbẹ̀rù OLUWA pé, ó wà títí lae, ìdájọ́ OLUWA tọ́, òdodo ni gbogbo wọn. Wọ́n wuni ju wúrà lọ, àní ju ojúlówó wúrà lọ; wọ́n sì dùn ju oyin, àní, wọ́n dùn ju oyin tí ń kán láti inú afárá lọ. Pẹlupẹlu àwọn ni wọ́n ń ki èmi iranṣẹ rẹ, nílọ̀, èrè pupọ sì ń bẹ ninu pípa wọ́n mọ́. Ṣugbọn ta ni lè mọ àṣìṣe ara rẹ̀? Wẹ̀ mí mọ́ ninu àṣìṣe àìmọ̀ mi. Pa èmi iranṣẹ rẹ mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀-ọ́n-mọ̀-dá; má jẹ́ kí wọ́n jọba lórí mi. Nígbà náà ni ara mi yóo mọ́, n kò sì ní jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ńlá. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi, ati àṣàrò ọkàn mi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ojú rẹ, OLUWA ibi ààbò mi ati olùràpadà mi. OLUWA óo dá ọ lóhùn ní ọjọ́ ìpọ́njú, orúkọ Ọlọrun Jakọbu óo dáàbò bò ọ́. Yóo rán olùrànlọ́wọ́ sí ọ láti ilé mímọ́ rẹ̀ wá, yóo sì tì ọ́ lẹ́yìn láti Sioni wá. Yóo ranti gbogbo ẹbọ ọrẹ rẹ, yóo sì gba ẹbọ sísun rẹ. Yóo fún ọ ní ohun tí o fẹ́ ninu ọkàn rẹ, yóo sì mú gbogbo èrò rẹ ṣẹ. Ìhó ayọ̀ ni a óo hó nígbà tí o bá ṣẹgun, ní orúkọ Ọlọrun wa ni a óo sì fi ọ̀págun wa sọlẹ̀; OLUWA yóo dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ. Mo wá mọ̀ nisinsinyii pé OLUWA yóo ran ẹni àmì òróró rẹ̀ lọ́wọ́; OLUWA yóo dá a lóhùn láti ọ̀run mímọ́ rẹ̀ wá yóo sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ fún un ní ìṣẹ́gun ńlá. Àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀lé kẹ̀kẹ́ ogun, àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀lé ẹṣin, ṣugbọn ní tiwa, àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ OLUWA Ọlọrun wa. Àwọn óo kọsẹ̀, wọn óo sì ṣubú, ṣugbọn àwa óo dìde, a óo sì dúró ṣinṣin. Fún ọba ní ìṣẹ́gun, OLUWA; kí o sì dá wa lóhùn nígbà tí a bá ń ké pè ọ́. Ọba ń yọ̀ nítorí agbára rẹ, OLUWA; inú rẹ̀ ń dùn lọpọlọpọ nítorí ríràn tí o ràn án lọ́wọ́! O ti fún un ní ohun tí ọkàn rẹ̀ ń fẹ́, o kò sì fi ohun tí ó ń tọrọ dù ú. O gbé ibukun dáradára pàdé rẹ̀; o fi adé ojúlówó wúrà dé e lórí. Ó bèèrè ẹ̀mí gígùn lọ́wọ́ rẹ; o fi fún un, àní, ọjọ́ gbọọrọ títí ayé. Òkìkí rẹ̀ pọ̀ nítorí pé o ràn án lọ́wọ́; o sì fi iyì ati ọlá ńlá jíǹkí rẹ̀. Nítòótọ́ o sọ ọ́ di ẹni ibukun títí lae; o sì mú kí inú rẹ̀ dùn nítorí pé o wà pẹlu rẹ̀. Nítorí pé ọba gbẹ́kẹ̀lé OLUWA; a kò ní ṣí i ní ipò pada, nítorí ìfẹ́ Ọ̀gá Ògo tí kì í yẹ̀. Ọwọ́ rẹ yóo tẹ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ; ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóo tẹ gbogbo àwọn tí ó kórìíra rẹ. O óo jó wọn run bí iná ìléru, nígbà tí o bá yọ sí wọn. OLUWA yóo gbé wọn mì ninu ibinu rẹ̀; iná yóo sì jó wọn ní àjórun. O óo pa àwọn ọmọ wọn run lórí ilẹ̀ ayé, o óo sì run ìran wọn láàrin àwọn eniyan. Bí wọn bá gbèrò ibi sí ọ, tí wọ́n sì pète ìkà, wọn kò ní lè ṣe é. Nítorí pé o óo lé wọn sá; nígbà tí o bá fi ọfà rẹ sun ojú wọn. A gbé ọ ga, nítorí agbára rẹ, OLUWA! A óo máa kọrin, a óo sì máa yin agbára rẹ. Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀, tí o fi jìnnà sí mi, tí o kò gbọ́ igbe mi, kí o sì ràn mí lọ́wọ́? Ọlọrun mi, mo kígbe pè ọ́ lọ́sàn-án, ṣugbọn o ò dáhùn; mo kígbe lóru, n ò sì dákẹ́. Sibẹ Ẹni Mímọ́ ni ọ́, o gúnwà, Israẹli sì ń yìn ọ́. Ìwọ ni àwọn baba wa gbẹ́kẹ̀lé; wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọ, o sì gbà wọ́n. Wọ́n kígbe pè ọ́, o sì gbà wọ́n; ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀lé, ojú kò sì tì wọ́n. Ṣugbọn kòkòrò lásán ni mí, n kì í ṣe eniyan; ayé kẹ́gàn mi, gbogbo eniyan sì ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà. Gbogbo àwọn tí ó rí mi ní ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́; wọ́n ń yọ ṣùtì sí mi; wọ́n sì ń mi orí pé, “Ṣebí OLUWA ni ó fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ lé lọ́wọ́; kí OLUWA ọ̀hún yọ ọ́, kí ó sì gbà á là, ṣebí inú rẹ̀ dùn sí i!” Bẹ́ẹ̀ sì ni ìwọ ni o mú mi jáde láti inú ìyá mi; ìwọ ni o sì mú mi wà láìséwu nígbà tí mo wà ní ọmọ ọmú. Ìwọ ni wọ́n bí mi lé lọ́wọ́; ìwọ ni Ọlọrun mi láti ìgbà tí ìyá mi ti bí mi. Má jìnnà sí mi, nítorí pé ìyọnu wà nítòsí, kò sì sí ẹni tí yóo ràn mí lọ́wọ́. Àwọn ọ̀tá yí mi ká bí akọ mààlúù, wọ́n yí mi ká bí akọ mààlúù Baṣani tó lágbára. Wọ́n ya ẹnu wọn sí mi bí kinniun, bí kinniun tí ń dọdẹ kiri tí ń bú ramúramù. Agbára mi ti lọ, ó ti ṣàn dànù bí omi, gbogbo egungun mi ti yẹ̀ lóríkèéríkèé; ọkàn mi dàbí ìda, ó ti yọ́. Okun inú mi ti gbẹ bí àpáàdì, ahọ́n mi sì ti lẹ̀ mọ́ mi lẹ́nu; o ti fi mí sílẹ̀ sinu eruku isà òkú. Àwọn eniyan burúkú yí mi ká bí ajá; àwọn aṣebi dòòyì ká mi; wọ́n fa ọwọ́ ati ẹsẹ̀ mi ya. Mo lè ka gbogbo egungun mi wọ́n tẹjúmọ́ mi; wọ́n ń fojú burúkú wò mí. Wọ́n pín aṣọ mi láàrin ara wọn, wọ́n ṣẹ́ gègé nítorí ẹ̀wù mi. Ṣugbọn ìwọ, OLUWA, má jìnnà sí mi! Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi, ṣe gírí láti ràn mí lọ́wọ́! Gba ẹ̀mí mi lọ́wọ́ idà, gbà mí lọ́wọ́ àwọn ajá! Já mi gbà kúrò lẹ́nu kinniun nnì gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìwo ẹhànnà mààlúù! N óo ròyìn orúkọ rẹ fún àwọn ará mi; láàrin àwùjọ àwọn eniyan ni n óo sì ti máa yìn ọ́: Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ máa yìn ín! Ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, ẹ fi ògo fún un, ẹ dúró tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ níwájú rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ọmọ Israẹli! Nítorí pé kò fi ojú pa ìjìyà àwọn tí à ń jẹ níyà rẹ́; kò sì ṣá wọn tì, bẹ́ẹ̀ ni kò fi ojú pamọ́ fún wọn, ṣugbọn ó gbọ́ nígbà tí wọ́n ké pè é. Ìwọ ni n óo máa yìn láàrin àwùjọ àwọn eniyan; n óo san ẹ̀jẹ́ mi láàrin àwọn tí ó bẹ̀rù OLUWA. Àwọn tí ojú ń pọ́n yóo jẹ àjẹyó; àwọn tí ń wá OLUWA yóo yìn ín! Kí ẹ̀mí wọn ó gùn! Gbogbo ayé ni yóo ranti OLUWA wọn yóo sì pada sọ́dọ̀ rẹ̀; gbogbo ẹ̀yà àwọn orílẹ̀-èdè ni yóo sì júbà níwájú rẹ̀. Nítorí OLUWA ló ni ìjọba, òun ní ń jọba lórí gbogbo orílẹ̀-èdè. Gbogbo àwọn agbéraga láyé ni yóo wólẹ̀ níwájú rẹ̀; gbogbo ẹni tí yóo fi ilẹ̀ bora bí aṣọ ni yóo wólẹ̀ níwájú rẹ̀, àní, gbogbo àwọn tí kò lè dá sọ ara wọn di alààyè. Ìran tí ń bọ̀ yóo máa sìn ín; àwọn eniyan yóo máa sọ̀rọ̀ OLUWA fún àwọn ìran tí ń bọ̀. Wọn óo máa kéde ìgbàlà rẹ̀ fún àwọn ọmọ tí a kò tíì bí, pé, “OLUWA ló ṣe é.” OLUWA ni Olùṣọ́-aguntan mi, n kò ní ṣe àìní ohunkohun. Ó mú mi dùbúlẹ̀ ninu pápá koríko tútù, ó mú mi lọ sí ibi tí omi ti dákẹ́ rọ́rọ́; ó sọ agbára mi dọ̀tun. Ó tọ́ mi sí ọ̀nà òdodo nítorí orúkọ rẹ̀. Àní, bí mo tilẹ̀ ń rìn ninu òkùnkùn létí bèbè ikú, n kò ní bẹ̀rù ibi kankan; nítorí tí o wà pẹlu mi; ọ̀gọ rẹ ati ọ̀pá rẹ ń fi mí lọ́kàn balẹ̀. O gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú mi, níṣojú àwọn ọ̀tá mi; o da òróró sí mi lórí; o sì bu ife mi kún ní àkúnwọ́sílẹ̀. Dájúdájú, ire ati àánú yóo máa tẹ̀lé mi kiri, ní gbogbo ọjọ́ ayé mi; èmi óo sì máa gbé inú ilé OLUWA laelae. OLUWA ló ni ilẹ̀ ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀, òun ló ni ayé, ati gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀; nítorí pé òun ló fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí òkun, ó sì gbé e kalẹ̀ lórí ìṣàn omi. Ta ló lè gun orí òkè OLUWA lọ? Ta ló sì lè dúró ninu ibi mímọ́ rẹ̀? Ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ mọ́, tí inú rẹ̀ sì funfun, tí kò gbẹ́kẹ̀lé oriṣa lásánlàsàn, tí kò sì búra èké. Òun ni yóo rí ibukun gbà lọ́dọ̀ OLUWA, tí yóo sì rí ìdáláre gbà lọ́wọ́ Ọlọrun, Olùgbàlà rẹ̀. Irú wọn ni àwọn tí ń wá OLUWA, àní àwọn tí ń wá ojurere Ọlọrun Jakọbu. Ẹ ṣí sílẹ̀ gbayau, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn, ẹ wà ní ṣíṣí sílẹ̀, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé, kí Ọba ògo lè wọlé. Ta ni Ọba ògo yìí? OLUWA tí ó ní ipá tí ó sì lágbára, OLUWA tí ó lágbára lógun. Ẹ ṣí sílẹ̀ gbayau, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn, ẹ wà ní ṣíṣí sílẹ̀, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé, kí Ọba ògo lè wọlé. Ta ni Ọba ògo yìí? OLUWA àwọn ọmọ ogun, òun ni Ọba ògo náà. OLUWA, ìwọ ni mo gbé ojú ẹ̀bẹ̀ sókè sí. Ọlọrun mi, ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé, má jẹ́ kí ojú ó tì mí; má jẹ́ kí ọ̀tá ó yọ̀ mí. OLUWA, má jẹ́ kí ojú ó ti ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọ; àwọn ọ̀dàlẹ̀ eniyan ni kí ojú ó tì. Fi ọ̀nà rẹ hàn mí, OLUWA, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ. Tọ́ mi sí ọ̀nà òtítọ́ rẹ, sì máa kọ́ mi, nítorí ìwọ ni Ọlọrun olùgbàlà mi; ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé ní ọjọ́ gbogbo. OLUWA, ranti àánú rẹ, ati ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, nítorí wọ́n ti wà ọjọ́ ti pẹ́. Má ranti ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ti ṣẹ̀ ní ìgbà èwe mi, tabi ibi tí mo ti kọjá ààyè mi; ranti mi, OLUWA, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, ati nítorí oore rẹ. Olóore ati olódodo ni OLÚWA, nítorí náà ni ó ṣe ń fi ọ̀nà han àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. A máa tọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ láti ṣe ohun tí ó tọ́, a sì máa kọ́ wọn ní ìlànà rẹ̀. Gbogbo ọ̀nà OLUWA ni ó kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́, fún àwọn tí ń pa majẹmu ati òfin rẹ̀ mọ́. Nítorí orúkọ rẹ, OLUWA, dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí, nítorí mo jẹ̀bi lọpọlọpọ. Ẹni tí ó bá bẹ̀rù OLUWA ni OLUWA yóo kọ́ ní ọ̀nà tí yóo yàn. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóo ní ọpọlọpọ ọrọ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóo sì jogún ilẹ̀ náà. Àwọn tí ó bá bẹ̀rù OLUWA ni OLUWA ń mú ní ọ̀rẹ́, a sì máa fi majẹmu rẹ̀ hàn wọ́n. OLUWA ni mò ń wò lójú nígbà gbogbo, nítorí òun ni yóo yọ ẹsẹ̀ mi kúrò ninu àwọ̀n. Kọjú sí mi kí o sì ṣàánú mi; nítorí n kò lẹ́nìkan, ojú sì ń pọ́n mi. Mú ìdààmú ọkàn mi kúrò; kí o sì yọ mí ninu gbogbo ìpọ́njú mi. Wo ìpọ́njú ati ìdààmú mi, kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí. Wo iye ọ̀tá tí èmi nìkan ní, ati irú ìkórìíra ìkà tí wọ́n kórìíra mi. Pa mí mọ́, kí o sì gbà mí; má jẹ́ kí ojú kí ó tì mí, nítorí ìwọ ni mo sá di. Nítorí pípé mi ati òdodo mi, pa mí mọ́, nítorí pé ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé. Ọlọrun, ra Israẹli pada, kúrò ninu gbogbo ìyọnu rẹ̀. Dá mi láre, OLUWA, nítorí ninu ìwà pípé ni mò ń rìn, mo sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA láìṣiyèméjì. Yẹ̀ mí wò, OLUWA, dán mi wò; yẹ inú mi wò, sì ṣe akiyesi ọkàn mi. Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ni mo tẹjúmọ́, mo sì ń fi òtítọ́ bá ọ rìn. N kò jókòó ti àwọn èké, n kò sì gba ìmọ̀ràn àwọn ẹlẹ́tàn; mo kórìíra wíwà pẹlu àwọn aṣebi, n kò sì jẹ́ bá àwọn eniyan burúkú da nǹkan pọ̀. Ọwọ́ mi mọ́, n kò ní ẹ̀bi, OLUWA, mo sì ń jọ́sìn yí pẹpẹ rẹ ká. Mò ń kọ orin ọpẹ́ sókè, mo sì ń ròyìn iṣẹ́ ìyanu rẹ. OLUWA, mo fẹ́ràn ilé rẹ, tí ò ń gbé, ati ibi tí ògo rẹ wà. Má pa mí run pẹlu àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, má sì gba ẹ̀mí mi pẹlu ti àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ìpànìyàn, àwọn tí ọwọ́ wọn kún fún iṣẹ́ ibi, tí ọwọ́ ọ̀tún wọn sì kún fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀. Ṣugbọn ní tèmi, èmi ń rìn ninu ìwà pípé; rà mí pada, kí o sì ṣàánú mi. Mo dúró lórí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú; láwùjọ ọ̀pọ̀ eniyan ni n óo máa yin OLUWA. OLUWA ni ìmọ́lẹ̀ ati ìgbàlà mi; ta ni n óo bẹ̀rù? OLUWA ni ààbò ẹ̀mí mi, ẹ̀rù ta ni yóo bà mí? Nígbà tí àwọn aṣebi bá ń gbógun bọ̀ wá bá mi, tí wọ́n fẹ́ pa mí, àwọn alátakò ati àwọn ọ̀tá mi, wọn óo kọsẹ̀, wọn óo sì ṣubú. Bí ogun tilẹ̀ dó tì mí àyà mi kò ní já. Bí wọ́n tilẹ̀ gbé ogun wá bá mi, sibẹ, ọkàn mi kò ní mì. Ohun kan ni mo ti tọrọ lọ́dọ̀ OLUWA, òun ni n óo sì máa lépa: Kí n lè máa gbé inú ilé OLUWA ní gbogbo ọjọ́ ayé mi, kí n lè máa wo ẹwà OLUWA, kí n sì máa fi tọkàntọkàn sìn ín ninu tẹmpili rẹ̀. Nítorí pé, nígbà tí ìpọ́njú bá dé, yóo fi mí pamọ́ sinu àgọ́ rẹ̀, lábẹ́ ààbò, ninu àgọ́ rẹ̀, ni yóo fi mí pamọ́ sí; yóo sì gbé mi sókè ka orí àpáta. Nisinsinyii n óo ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá mi tí ó yí mi ká; n óo rúbọ ninu àgọ́ rẹ̀ pẹlu ìhó ayọ̀, n óo sì kọ orin aládùn sí OLUWA. Gbọ́ OLUWA, nígbà tí mo bá ń kígbe pè ọ́; ṣàánú mi kí o sì dá mi lóhùn. Nígbà tí o wí pé, “Ẹ máa wá ojú mi.” Ọkàn mi dá ọ lóhùn pé, “Ojú rẹ ni n óo máa wá, OLUWA, má fi ojú pamọ́ fún mi!” Má fi ibinu lé èmi iranṣẹ rẹ kúrò, ìwọ tí o ti ń ràn mí lọ́wọ́, má ta mí nù, má sì ṣá mi tì, Ọlọrun ìgbàlà mi. Bí baba ati ìyá mi tilẹ̀ kọ̀ mí sílẹ̀, OLUWA yóo tẹ́wọ́gbà mí. Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, OLUWA, kí o sì tọ́ mi sí ọ̀nà títẹ́jú rẹ, nítorí àwọn ọ̀tá mi. Má fi mí lé ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi lọ́wọ́; nítorí pé àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde sí mi, ètè wọn sì kún fún ọ̀rọ̀ ìkà. Mo gbàgbọ́ pé n óo rí oore OLUWA gbà ní ilẹ̀ alààyè. Dúró de OLUWA, ṣe bí akin, kí o sì mú ọkàn gírí, àní, dúró de OLUWA. Ìwọ ni mo kígbe pè, OLUWA, ìwọ ni ààbò mi, má di etí sí mi. Nítorí bí o bá dákẹ́ sí mi n óo dàbí àwọn òkú, tí wọ́n ti lọ sinu kòtò. Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi, bí mo ti ń kígbe sí ọ pé kí o ràn mí lọ́wọ́; tí mo gbé ọwọ́ mi sókè sí ìhà ilé mímọ́ rẹ. Má ṣe kó mi lọ pẹlu àwọn eniyan burúkú, pẹlu àwọn tí ń ṣe iṣẹ́ ibi, àwọn tí ń bá àwọn aládùúgbò wọn sọ ọ̀rọ̀ alaafia, ṣugbọn tí ètekéte ń bẹ ninu ọkàn wọn. San án fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn, àní gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ burúkú wọn; san án fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn, fún wọn ní èrè tí ó tọ́ sí wọn. Nítorí pé wọn kò ka iṣẹ́ OLUWA sí, wọn kò sì bìkítà fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, OLUWA yóo sọ wọ́n di ilẹ̀, kò sì ní gbé wọn dìde mọ́. Ẹni ìyìn ni OLUWA! Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi. OLUWA ni agbára ati asà mi, òun ni mo gbẹ́kẹ̀lé; ó ràn mí lọ́wọ́, ọkàn mi sì kún fún ayọ̀; mo sì fi orin ìyìn dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. OLUWA ni agbára àwọn eniyan rẹ̀; òun ni ààbò ìgbàlà fún ẹni àmì òróró rẹ̀. Gba àwọn eniyan rẹ là, OLUWA, kí o sì bukun ilẹ̀ ìní rẹ. Jẹ́ olùṣọ́-aguntan wọn, kí o sì máa tọ́jú wọn títí lae. Ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run, ẹ fi ògo fún OLUWA, ẹ gbé agbára rẹ̀ lárugẹ. Ẹ fún OLUWA ní ògo tí ó yẹ orúkọ rẹ̀, ẹ máa sin OLUWA ninu ẹwà mímọ́ rẹ̀. À ń gbọ́ ohùn OLUWA lójú omi òkun, Ọlọrun ológo ń sán ààrá, Ọlọrun ń sán ààrá lójú alagbalúgbú omi. Ohùn OLUWA lágbára, ohùn OLUWA kún fún ọlá ńlá. Ohùn OLUWA ń fọ́ igi kedari, OLUWA ń fọ́ igi kedari ti Lẹbanoni. Ó ń mú kí òkè Lẹbanoni ta pọ́núnpọ́nún bí ọmọ mààlúù, ó sì mú kí òkè Sirioni máa fò bí akọ ọmọ mààlúù-igbó. Ohùn OLUWA ń yọ iná lálá. Ohùn OLUWA ń mi aṣálẹ̀; OLUWA ń mi aṣálẹ̀ Kadeṣi. Ohùn OLUWA a máa mú abo àgbọ̀nrín bí, a máa wọ́ ewé lára igi oko; gbogbo eniyan ń kígbe ògo rẹ̀ ninu Tẹmpili rẹ̀. OLUWA jókòó, ó gúnwà lórí ìkún omi; OLUWA jókòó, ó gúnwà bí ọba títí lae. OLUWA yóo fún àwọn eniyan rẹ̀ ní agbára; OLUWA yóo fún wọn ní ibukun alaafia. N óo yìn ọ́, OLUWA, nítorí pé o ti yọ mí jáde; o kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi ó yọ̀ mí. OLUWA, Ọlọrun mi, mo ké pè ọ́, o sì wò mí sàn. OLUWA, o ti yọ mí kúrò ninu isà òkú o sọ mí di ààyè láàrin àwọn tí wọ́n ti wọ inú kòtò. Ẹ kọ orin ìyìn sí OLUWA, ẹ̀yin olùfọkànsìn rẹ̀, kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ̀. Nítorí pé fún ìgbà díẹ̀ ni ibinu rẹ̀, ṣugbọn títí ayé ni ojurere rẹ̀; eniyan lè máa sọkún títí di alẹ́, ṣugbọn ayọ̀ ń bọ̀ fún un lówùúrọ̀. Nígbà tí ara rọ̀ mí, mo wí ninu ọkàn mi pé, kò sí ohun tí ó lè mì mí laelae. Nípa ojurere rẹ, OLUWA, o ti fi ìdí mi múlẹ̀ bí òkè ńlá; ṣugbọn nígbà tí o fi ojú pamọ́ fún mi, ìdààmú dé bá mi. Ìwọ ni mò ń ké pè, OLUWA, OLUWA, ìwọ ni mò ń bẹ̀. Anfaani wo ló wà ninu pé kí n kú? Èrè wo ló wà ninu pé kí n wọ inú kòtò? Ṣé erùpẹ̀ lè yìn ọ́? Ṣé ó lè sọ nípa òdodo rẹ? Gbọ́ OLUWA, kí o sì ṣàánú mi, OLUWA, ràn mí lọ́wọ́. O ti bá mi sọ ọ̀fọ̀ mi di ijó, o ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ kúrò lára mi, o sì ti dì mí ní àmùrè ayọ̀, kí ọkàn mi lè máa yìn ọ́ láìdákẹ́. OLUWA Ọlọrun mi, n óo máa fi ọpẹ́ fún ọ títí lae. OLUWA, ìwọ ni mo sá di, má jẹ́ kí ojú tì mí lae; gbà mí, nítorí olóòótọ́ ni ọ́. Dẹ etí sí mi, yára gbà mí. Jẹ́ àpáta ààbò fún mi; àní ilé ààbò tó lágbára láti gbà mí là. Ìwọ ni àpáta ati ilé ààbò mi; nítorí orúkọ rẹ, máa tọ́ mi kí o sì máa fọ̀nà hàn mí. Yọ mí kúrò ninu àwọ̀n tí wọ́n dẹ pamọ́ dè mí, nítorí ìwọ ni ẹni ìsádi mi. Ìwọ ni mo fi ẹ̀mí mi lé lọ́wọ́, o ti rà mí pada, OLUWA, Ọlọrun, olóòótọ́. Mo kórìíra àwọn tí ń bọ oriṣa lásánlàsàn, ṣugbọn OLUWA ni èmi gbẹ́kẹ̀lé. N óo máa yọ̀, inú mi óo sì máa dùn, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀; nítorí pé o ti rí ìpọ́njú mi, o sì mọ ìṣòro mi. O ò fi mí lé ọ̀tá lọ́wọ́, o sì ti fi ẹsẹ̀ mi lé ilẹ̀ tí ó tẹ́jú. Ṣàánú mi, OLUWA, nítorí pé mo wà ninu ìṣòro. Ìbànújẹ́ sọ ojú mi di bàìbàì; àárẹ̀ sì mú ọkàn ati ara mi. Nítorí pé ìbànújẹ́ ni mo fi ń lo ayé mi; ìmí ẹ̀dùn ni mo sì fi ń lo ọdún kan dé ekeji. Ìpọ́njú ti gba agbára mi; gbogbo egungun mi sì ti di hẹ́gẹhẹ̀gẹ. Ẹni ẹ̀gàn ni mí láàrin gbogbo àwọn ọ̀tá mi, àwòsọkún ni mí fún àwọn aládùúgbò. Mo di àkòtagìrì fún àwọn ojúlùmọ̀ mi, àwọn tí ó rí mi lóde sì ń sá fún mi. Mo di ẹni ìgbàgbé bí ẹni tí ó ti kú; mo dàbí àkúfọ́ ìkòkò. Mò ń gbọ́ tí ọ̀pọ̀ eniyan ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, bí wọ́n ti ń gbìmọ̀ pọ̀ nípa mi, tí wọ́n sì ń pète ati pa mí; wọ́n ń ṣẹ̀rù bà mí lọ́tùn-ún lósì. Ṣugbọn, mo gbẹ́kẹ̀lé ọ, OLUWA, Mo ní, “Ìwọ ni Ọlọrun mi.” Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ; gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, ati lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi. Jẹ́ kí èmi iranṣẹ rẹ rí ojurere rẹ, gbà mí là, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀. Má jẹ́ kí ojú tì mí, OLUWA, nítorí ìwọ ni mò ń ké pè. Jẹ́ kí ojú ti àwọn eniyan burúkú; jẹ́ kí ẹnu wọn wọ wòwò títí wọ ibojì. Jẹ́ kí àwọn òpùrọ́ yadi, àní àwọn tí ń fi ìgbéraga ati ẹ̀gàn sọ̀rọ̀ àìdára nípa olódodo. Háà! Ohun rere mà pọ̀ lọ́wọ́ rẹ o tí o ti sọ lọ́jọ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ, tí o sì ti pèsè ní ìṣojú àwọn ọmọ eniyan, fún àwọn tí ó sá di ọ́. O fi ìyẹ́ apá rẹ ṣíji bò wọ́n; o pa wọ́n mọ́ kúrò ninu rìkíṣí àwọn eniyan; o sì pa wọ́n mọ́ lábẹ́ ààbò rẹ, kúrò lọ́wọ́ ẹnu àwọn ẹlẹ́jọ́ wẹ́wẹ́. Ẹni ìyìn ni OLUWA, nítorí pé, lọ́nà ìyanu, ó fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn mí, nígbà tí ilẹ̀ ká mi mọ́. Ẹ̀rù bà mí, mo sì sọ pé, “A lé mi jìnnà kúrò ní iwájú rẹ.” Ṣugbọn o gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi nígbà tí mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́. Ẹ fẹ́ràn OLUWA, gbogbo ẹ̀yin olódodo, OLUWA a máa ṣọ́ àwọn olóòótọ́, a sì máa san àlékún ẹ̀san fún àwọn agbéraga. Ẹ múra gírí, kí ẹ sì mọ́kàn le, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí a dárí ìrékọjá rẹ̀ jì, tí a bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí OLUWA kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí lọ́rùn, tí ẹ̀tàn kò sì sí ninu ọkàn rẹ̀. Nígbà tí n kò jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi, ó rẹ̀ mí wá láti inú, nítorí kíkérora tí mò ń kérora ní gbogbo ìgbà. Nítorí tọ̀sán-tòru ni o fi ń jẹ mí níyà; gbogbo agbára mi ló lọ háú, bí omi tíí gbẹ lákòókò ẹ̀ẹ̀rùn. Mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún ọ; n kò sì fi àìdára mi pamọ́ fún ọ. Mo ní, “Èmi óo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Oluwa,” o sì dáríjì mí. Nítorí náà, kí gbogbo olódodo máa gbadura sí ọ; ní àkókò tí ìpọ́njú bá ń yí lura wọn bí ìṣàn omi ńlá, kò ní dé ọ̀dọ̀ wọn. Ìwọ ni ibi ìsásí mi; o pa mí mọ́ kúrò ninu ìṣòro; o sì fi ìgbàlà yí mi ká. N óo kọ́ ọ, n óo sì tọ́ ọ sí ọ̀nà tí o óo rìn; n óo máa gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn; n óo sì máa mójútó ọ. Má ṣe dàbí ẹṣin tabi ìbaaka, tí kò ni ọgbọ́n ninu, tí a gbọdọ̀ kó ìjánu sí lẹ́nu kí ó tó lè gbọ́ ti oluwa rẹ̀. Ìrora pọ̀ fún àwọn eniyan burúkú, ṣugbọn ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ni ó yí àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA ká. Ẹ máa yọ̀ ninu OLUWA; ẹ fò fún ayọ̀, ẹ̀yin olódodo; kí ẹ sì hó fún ayọ̀, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́kàn mímọ́. Ẹ máa yọ̀ ninu OLUWA, ẹ̀yin olódodo! Yíyin OLUWA ni ó yẹ ẹ̀yin olóòótọ́. Ẹ fi gòjé yin OLUWA, ẹ fi hapu olókùn mẹ́wàá kọ orin sí i. Ẹ kọ orin titun sí i, ẹ fi ohun èlò ìkọrin olókùn dárà, kí ẹ sì hó ìhó ayọ̀. Nítorí ọ̀rọ̀ OLUWA dúró ṣinṣin; òtítọ́ sì ni ó fi ń ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ̀. OLUWA fẹ́ràn òdodo ati ẹ̀tọ́; ayé kún fún ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀. Ọ̀rọ̀ ni OLUWA fi dá ojú ọ̀run, èémí ẹnu rẹ̀ ni ó sì fi dá oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀. Ó wọ́ gbogbo omi òkun jọ bí òkìtì; ó pa gbogbo omi inú àwọn ibú pọ̀ bí ẹni pé ó rọ ọ́ sinu àgbá ńlá. Kí gbogbo ayé bẹ̀rù OLUWA, kí gbogbo aráyé dúró níwájú rẹ̀ pẹlu ọ̀wọ̀ ati ìbẹ̀rù! Nítorí pé OLUWA sọ̀rọ̀, ayé wà; ó pàṣẹ, ayé sì dúró. OLUWA sọ ìmọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè di asán; ó sì mú kí ètò àwọn eniyan já sófo. Ètò OLUWA wà títí lae, èrò ọkàn rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran. Ayọ̀ ń bẹ fún orílẹ̀-èdè tí OLUWA jẹ́ Ọlọrun wọn, àní àwọn eniyan tí ó yàn gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀! OLUWA bojúwo ilẹ̀ láti ọ̀run, ó rí gbogbo eniyan; láti orí ìtẹ́ rẹ̀ tí ó gúnwà sí, ó wo gbogbo aráyé. Òun ni ó dá ọkàn gbogbo wọn, tí ó sì ń mójútó gbogbo ìṣe wọn. Kì í ṣe pípọ̀ tí àwọn ọmọ ogun pọ̀ ní ń gba ọba là; kì í sì í ṣe ọ̀pọ̀ agbára níí gba jagunjagun là. Asán ni igbẹkẹle agbára ẹṣin ogun; kìí ṣe agbára tí ẹṣin ní, ló lè gbani là. Wò ó! OLUWA ń ṣọ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àní àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, kí ó lè gba ọkàn wọn lọ́wọ́ ikú, kí ó sì mú wọn wà láàyè lákòókò ìyàn. Ọkàn wa ní ìrètí lọ́dọ̀ OLUWA; òun ni olùrànlọ́wọ́ ati ààbò wa. A láyọ̀ ninu rẹ̀, nítorí pé a gbẹ́kẹ̀lé orúkọ mímọ́ rẹ̀. OLUWA, jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ wà lórí wa bí a ti gbẹ́kẹ̀lé ọ. N óo máa yin OLUWA ní gbogbo ìgbà; ìyìn rẹ̀ yóo máa wà ní ẹnu mi nígbà gbogbo. OLUWA ni èmi óo máa fi yangàn; kí inú àwọn olùpọ́njú máa dùn nígbà tí wọ́n bá gbọ́. Ẹ bá mi gbé OLUWA ga, ẹ jẹ́ kí á jùmọ̀ gbé orúkọ rẹ̀ lékè! Mo ké pe OLUWA, ó sì dá mi lóhùn, ó sì gbà mí lọ́wọ́ gbogbo ohun tí ń bà mí lẹ́rù. Wọ́n gbójú sókè sí OLUWA, wọ́n láyọ̀; ojú kò sì tì wọ́n. Olùpọ́njú ké pe OLUWA, OLUWA gbọ́ ohùn rẹ̀, ó sì gbà á ninu gbogbo ìpọ́njú rẹ̀. Angẹli OLUWA yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká, a sì máa gbà wọ́n. Tọ́ ọ wò, kí o sì rí i pé rere ni OLUWA! Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá sá di í! Ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ̀yin eniyan mímọ́ rẹ̀, nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀! Àwọn ọmọ kinniun a máa ṣe aláìní, ebi a sì máa pa wọ́n; ṣugbọn àwọn tí wọ́n bá ń wá OLUWA kò ní ṣe aláìní ohun rere kankan. Ẹ wá, ẹ̀yin ọmọ, ẹ tẹ́tí sí mi, n óo kọ yín ní ìbẹ̀rù OLUWA. Ta ni ń fẹ́ ìyè ninu yín, tí ń fẹ́ ẹ̀mí gígùn, tí ó fẹ́ pẹ́ láyé? Ẹ ṣọ́ ẹnu yín, ẹ má sọ̀rọ̀ burúkú, ẹ má sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ti ẹnu yín jáde. Ẹ yàgò fún ibi, rere ni kí ẹ máa ṣe; ẹ máa wá alaafia, kí ẹ sì máa lépa rẹ̀. OLUWA ń ṣọ́ àwọn olódodo, Ó sì ń dẹ etí sí igbe wọn. OLUWA fojú sí àwọn aṣebi lára, láti pa wọ́n rẹ́, kí á má sì ṣe ranti wọn mọ́ lórí ilẹ̀ ayé. Nígbà tí olódodo bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́, OLUWA a máa gbọ́, a sì máa gbà wọ́n kúrò ninu gbogbo ìyọnu wọn. OLUWA wà nítòsí àwọn tí ọkàn wọn bàjẹ́, a sì máa gba àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn là. Ìpọ́njú olódodo a máa pọ̀; ṣugbọn OLUWA a máa kó o yọ ninu gbogbo wọn. A máa pa gbogbo egungun rẹ̀ mọ́; kì í jẹ́ kí ọ̀kankan fọ́ ninu wọn. Ibi ni yóo pa eniyan burúkú; a óo sì dá àwọn tí ó kórìíra olódodo lẹ́bi. OLUWA ra ẹ̀mí àwọn iranṣẹ rẹ̀ pada; ẹnikẹ́ni tí ó bá sá di í kò ní jẹ̀bi. OLUWA, gbógun ti àwọn tí ń gbógun tì mí; gbé ìjà ko àwọn tí ń bá mi jà! Gbá asà ati apata mú, dìde, kí o sì ràn mí lọ́wọ́! Fa ọ̀kọ̀ yọ kí o sì dojú kọ àwọn tí ń lépa mi! Ṣe ìlérí fún mi pé, ìwọ ni olùgbàlà mi. Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn tí ń lépa ẹ̀mí mi, kí wọn ó tẹ́! Jẹ́ kí àwọn tí ń gbìmọ̀ ibi sí mi dààmú, kí wọ́n sì sá pada sẹ́yìn! Kí wọ́n dàbí fùlùfúlù ninu afẹ́fẹ́, kí angẹli OLUWA máa lé wọn lọ! Jẹ́ kí ojú ọ̀nà wọn ṣóòkùn, kí ó sì máa yọ̀, kí angẹli OLUWA máa lépa wọn! Nítorí wọ́n dẹ àwọ̀n sílẹ̀ fún mi láìnídìí, wọ́n sì gbẹ́ kòtò sílẹ̀ dè mí láìnídìí. Jẹ́ kí ìparun dé bá wọn lójijì, jẹ́ kí àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀ dè mí mú wọn; jẹ́ kí wọ́n kó sinu rẹ̀, kí wọ́n sì parun! Nígbà náà ni n óo máa yọ̀ ninu OLUWA, n óo sì yọ ayọ̀ ńlá nítorí ìgbàlà rẹ̀. N óo fi gbogbo ara wí pé, “OLUWA, ta ni ó dàbí rẹ? Ìwọ ni ò ń gba aláìlágbára lọ́wọ́ ẹni tí ó lágbára tí o sì ń gba aláìlágbára ati aláìní lọ́wọ́ ẹni tí ó fẹ́ fi wọ́n ṣe ìjẹ.” Àwọn tí ń fi ìlara jẹ́rìí èké dìde sí mi; wọ́n ń bi mí léèrè ohun tí n kò mọ̀dí. Wọ́n fi ibi san oore fún mi, ọkàn mi sì rẹ̀wẹ̀sì. Bẹ́ẹ̀ sì ni, ní tèmi, nígbà tí wọn ń ṣàìsàn, aṣọ ọ̀fọ̀ ni mo wọ̀; mo fi ààwẹ̀ jẹ ara mi níyà; mo gbadura pẹlu ìtẹríba patapata, bí ẹni pé mò ń ṣọ̀fọ̀ ọ̀rẹ́ mi, tabi arakunrin mi; mò ń lọ káàkiri, bí ẹni tí ń pohùnréré ẹkún ìyá rẹ̀, mo doríkodò, mo sì ń ṣọ̀fọ̀. Ṣugbọn nígbà tí èmi kọsẹ̀, wọ́n kó ara wọn jọ, wọ́n ń yọ̀, wọ́n kó tì mí; pàápàá jùlọ, àwọn àlejò tí n kò mọ̀ rí bẹ̀rẹ̀ sí purọ́ mọ́ mi léraléra. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí pẹ̀gàn mi, wọ́n ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà; wọ́n sì ń wò mí bíi pé kí n kú. OLUWA, yóo ti pẹ́ tó, tí o óo máa wò mí níran? Yọ mí kúrò ninu ogun tí wọn gbé tì mí, gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn kinniun! Nígbà náà ni n óo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ láàrin àwùjọ ọ̀pọ̀ eniyan; láàrin ọpọlọpọ eniyan ni n óo máa yìn ọ́. Má jẹ́ kí àwọn tí ń bá mi ṣọ̀tá láìnídìí yọ̀ mí, má sì jẹ́ kí àwọn tí ó kórìíra mi wò mí ní ìwò ẹ̀sín. Nítorí pé wọn kì í sọ̀rọ̀ alaafia sí àwọn tí wọn ń lọ jẹ́ẹ́jẹ́ wọn àfi kí wọ́n máa pète oríṣìíríṣìí ẹ̀tàn. Wọ́n la ẹnu, wọ́n ń pariwo lé mi lórí, wọ́n ń wí pé, “Ìn hín ìn, a rí ọ, ojú wa ló ṣe!” O ti rí i, OLUWA, má dákẹ́. OLUWA, má jìnnà sí mi. Paradà, OLUWA, jí gìrì sí ọ̀ràn mi, gbèjà mi, Ọlọrun mi, ati OLUWA mi! Dá mi láre, OLUWA, Ọlọrun mi, gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ; má sì jẹ́ kí wọ́n yọ̀ mí! Má jẹ́ kí wọ́n wí láàrin ara wọn pé, “Ìn hín ìn, ọwọ́ wa ba ohun tí a fẹ́!” Má jẹ́ kí wọn wí pé, “A rẹ́yìn ọ̀tá wa.” Jẹ́ kí ojú ti gbogbo àwọn tí ń yọ̀ pé ìpọ́njú dé bá mi; kí ìdààmú bá wọn; bá mi da aṣọ ìtìjú ati ẹ̀tẹ́ bo àwọn tí ń gbé àgbéré sí mi. Kí àwọn tí ń wá ìdáláre mi máa hó ìhó ayọ̀, kí inú wọn sì máa dùn, kí wọ́n máa wí títí ayé pé, “OLUWA tóbi, inú rẹ̀ dùn sí alaafia àwọn iranṣẹ rẹ̀.” Nígbà náà ni n óo máa sọ̀rọ̀ òdodo rẹ, n óo sì máa yìn ọ́ tọ̀sán-tòru. Ẹ̀ṣẹ̀ ń gbin lọ́kàn eniyan burúkú, kò sí ìbẹ̀rù Ọlọrun ninu èrò tirẹ̀. Nítorí pé lọ́kàn rẹ̀ a máa pọ́n ara rẹ̀, pé kò sí ẹni tí ó lè rí ẹ̀ṣẹ̀ òun, ká tó wá sọ pé yóo dá òun lẹ́bi. Ọ̀rọ̀ ìkà ati ẹ̀tàn ni ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀. Ó ti dáwọ́ ire ṣíṣe dúró; kò sì hu ìwà ọlọ́gbọ́n mọ́. A máa pète ìkà lórí ibùsùn rẹ̀; a máa rin ọ̀nà tí kò tọ́; kò sì kórìíra ibi. OLUWA, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ga kan ọ̀run; òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run. Òtítọ́ rẹ dàbí òkè ńlá; ìdájọ́ rẹ sì jìn bí ibú omi. OLUWA, àtènìyàn, àtẹranko ni ò ń gbàlà. Ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ níye lórí pupọ, Ọlọrun! Àwọn ọmọ eniyan a máa sá sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ. Wọ́n ń rí oúnjẹ jẹ ní àjẹyó ní ilé rẹ; nǹkan mímu tí ń ṣàn bí odò, ni o sì ń fún wọn mu. Nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ ni orísun ìyè wà; ninu ìmọ́lẹ̀ rẹ ni a ti ń rí ìmọ́lẹ̀. Túbọ̀ máa fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ han àwọn tí ó mọ̀ ọ́, sì máa fi òdodo rẹ han àwọn ọlọ́kàn mímọ́. Má jẹ́ kí àwọn agbéraga borí mi, má sì jẹ́ kí àwọn eniyan burúkú lé mi kúrò. Ẹ wo àwọn aṣebi níbi tí wọ́n ṣubú sí; wọ́n dà wólẹ̀, wọn kò sì le dìde. Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná nítorí àwọn eniyan burúkú; má sì jowú àwọn aṣebi; nítorí pé kíákíá ni wọn yóo gbẹ bí i koríko; wọn óo sì rọ bí ewé. Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA; kí o sì máa ṣe rere. Máa gbe ilẹ̀ náà; ewu kò sì ní wu ọ́. Jẹ́ kí inú rẹ máa dùn ninu OLUWA; yóo sì fún ọ ní ohun tí ọkàn rẹ ń fẹ́. Fi ọ̀nà rẹ lé OLUWA lọ́wọ́; gbẹ́kẹ̀lé e, yóo sì ṣe ohun tí ó yẹ. Yóo mú kí ìdáláre rẹ tàn bí ìmọ́lẹ̀; ẹ̀tọ́ rẹ yóo sì hàn kedere bí ọ̀sán gangan. Dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú OLUWA; fi sùúrù gbẹ́kẹ̀lé e. Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná nítorí ẹni tí nǹkan ń dára fún; tabi nítorí ẹni tí ń gbèrò ibi, tí ó sì ń ṣe é. Yẹra fún ibinu; sì yàgò fún ìrúnú. Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná; ibi ni àyọrísí rẹ̀. Nítorí pé a óo pa àwọn eniyan burúkú run; ṣugbọn àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA ni yóo jogún ilẹ̀ náà. Ẹ fún eniyan burúkú ní ìgbà díẹ̀ sí i, yóo pòórá; ẹ̀ báà wá a títí ní ààyè rẹ̀, kò ní sí níbẹ̀. Ṣugbọn àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ni yóo jogún ilẹ̀ náà: wọn óo máa gbádùn ara wọn; wọn óo sì ní alaafia lọpọlọpọ. Eniyan burúkú dìtẹ̀ mọ́ olódodo; ó sì ń wò ó bíi kíkú bíi yíyè. Ṣugbọn OLUWA ń fi eniyan burúkú rẹ́rìn-ín, nítorí ó mọ̀ pé ọjọ́ ìparun rẹ̀ ń bọ̀. Àwọn eniyan burúkú fa idà yọ, wọ́n sì kẹ́ ọfà wọn láti gba ẹ̀mí talaka ati aláìní, láti pa àwọn tí ń rìn lọ́nà ẹ̀tọ́. Ṣugbọn idà wọn ni o óo fi pa wọ́n, ọrun wọn yóo sì dá. Nǹkan díẹ̀ tí olódodo ní dára ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ àwọn eniyan burúkú. Nítorí OLUWA yóo ṣẹ́ apá eniyan burúkú, ṣugbọn yóo gbé olódodo ró. OLUWA a máa tọ́jú àwọn aláìlẹ́bi; ilẹ̀ ìní wọn yóo jẹ́ tiwọn títí lae. Ojú kò ní tì wọ́n nígbà tí àjálù bá dé; bí ìyàn tilẹ̀ mú, wọn óo jẹ, wọn óo yó. Ṣugbọn àwọn eniyan burúkú yóo ṣègbé; àwọn ọ̀tá OLUWA yóo pòórá bí ẹwà ewéko wọn óo parẹ́ bí èéfín tí í parẹ́. Bí eniyan burúkú bá yá owó, kò ní san; ṣugbọn ẹni rere ní ojú àánú, ó sì lawọ́. Nítorí pé àwọn tí Ọlọrun bá bukun ni yóo jogún ilẹ̀ náà, ṣugbọn àwọn tí ó bá fi gégùn-ún yóo parun. OLUWA níí darí ìgbésẹ̀ ẹni; a sì máa fi ẹsẹ̀ ẹni tí inú rẹ̀ bá dùn sí múlẹ̀. Bí ó tilẹ̀ ṣubú, kò ní lulẹ̀ lógèdèǹgbé, nítorí OLUWA yóo gbé e ró. Mo ti jẹ́ ọmọde rí; mo sì ti dàgbà: n kò tíì ri kí á kọ olódodo sílẹ̀, tabi kí ọmọ rẹ̀ máa tọrọ jẹ. Olódodo ní ojú àánú, a sì máa yáni ní nǹkan, ayọ̀ ń bẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀. Ẹ yẹra fún ibi; ẹ sì máa ṣe rere; kí ẹ lè wà ní ààyè yín títí lae. Nítorí OLUWA fẹ́ràn ẹ̀tọ́; kò ní kọ àwọn olùfọkànsìn rẹ̀ sílẹ̀. Yóo máa ṣọ́ wọn títí lae, ṣugbọn a óo pa àwọn ọmọ eniyan burúkú run. Àwọn ẹni rere ni yóo jogún ilẹ̀ náà; wọn óo sì máa gbé orí rẹ̀ títí lae. Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n níí máa jáde lẹ́nu ẹni rere, a sì máa sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́. Òfin Ọlọrun rẹ̀ wà ní ọkàn rẹ̀; ìrìn ẹsẹ̀ rẹ̀ kì í yà kúrò níbẹ̀. Eniyan burúkú ń ṣọ́ olódodo, ó ń wá ọ̀nà ati pa á. OLUWA kò ní fi olódodo lé e lọ́wọ́, tabi kí ó jẹ́ kí á dá olódodo lẹ́bi ní ilé ẹjọ́. Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, sì máa tọ ọ̀nà rẹ̀, yóo gbé ọ ga, kí o lè jogún ilẹ̀ náà; nígbà tí a bá pa àwọn eniyan burúkú run, o óo fojú rẹ rí i. Mo ti rí eniyan burúkú tí ń halẹ̀ mọ́ni, tí ó ga bí igi kedari ti Lẹbanoni. Ṣugbọn nígbà tí mo tún gba ibẹ̀ kọjá, mo wò ó, kò sí níbẹ̀ mọ́; mo wá a, ṣugbọn n kò rí i. Ṣe akiyesi ẹni pípé; sì wo olódodo dáradára, nítorí pé ìgbẹ̀yìn ẹni tí ń wá alaafia yóo dára. Ṣugbọn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo parun patapata, a óo sì run ọmọ àwọn eniyan burúkú. Ọ̀dọ̀ OLUWA ni ìgbàlà àwọn olódodo ti ń wá; òun ni alátìlẹ́yìn wọn ní àkókò ìṣòro. OLUWA a máa ràn wọ́n lọ́wọ́, a sì máa gbà wọ́n; a máa gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú, a sì máa gbà wọ́n là, nítorí pé òun ni wọ́n sá di. OLUWA, má fi ibinu bá mi wí! Má sì fi ìrúnú jẹ mí níyà! Nítorí pé ọfà rẹ ti wọ̀ mí lára, ọwọ́ rẹ sì ti bà mí. Kò sí ibìkan tí ó gbádùn ní gbogbo ara mi nítorí ibinu rẹ; kò sì sí alaafia ninu gbogbo egungun mi, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi. Ẹ̀ṣẹ̀ mi ti bò mí lórí mọ́lẹ̀; ó rìn mí mọ́lẹ̀ bí ẹrù ńlá tí ó wúwo jù fún mi. Ọgbẹ́ mi ń kẹ̀, ó sì ń rùn, nítorí ìwà òmùgọ̀ mi, Ìbànújẹ́ dorí mi kodò patapata, mo sì ń ṣọ̀fọ̀ kiri tọ̀sán-tòru. Gbogbo ẹ̀gbẹ́ mi ń gbóná fòò, kò sí ibìkan tí ó gbádùn lára mi. Àárẹ̀ mú mi patapata, gbogbo ara sì wó mi; mò ń kérora nítorí ẹ̀dùn ọkàn mi. OLUWA, gbogbo ìfẹ́ ọkàn mi ni o mọ̀, ìmí ẹ̀dùn mi kò sì pamọ́ fún ọ. Àyà mi ń lù pì pì pì, ó rẹ̀ mí láti inú wá; ojú mi sì ti di bàìbàì. Àwọn ọ̀rẹ́ ati àwọn ẹlẹgbẹ́ mi takété sí mi nítorí àrùn mi, àwọn ẹbí mi sì dúró lókèèrè réré. Àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí mi dẹ tàkúté sílẹ̀ dè mí, àwọn tí ń wá ìpalára mi ń sọ̀rọ̀ ìparun mi, wọ́n sì ń pète àrékérekè tọ̀sán-tòru. Ṣugbọn mo ṣe bí adití, n kò gbọ́, mo dàbí odi tí kò le sọ̀rọ̀. Àní, mo dàbí ẹni tí kò gbọ́rọ̀, tí kò sì ní àwíjàre kan lẹ́nu. Ṣugbọn, OLUWA, ìwọ ni mò ń dúró dè; OLUWA, Ọlọrun mi, ìwọ ni o óo dá mi lóhùn. Nítorí tí mò ń gbadura pé, kí àwọn tí ń pẹ̀gàn mi má yọ̀ mí nígbà tí ẹsẹ̀ mi bá yẹ̀. Nítorí pé mo ti fẹ́rẹ̀ ṣubú, mo sì wà ninu ìrora nígbà gbogbo. Mo jẹ́wọ́ àṣìṣe mi, mo sì káàánú fún ẹ̀ṣẹ̀ mi. Àwọn tí ń bá mi ṣọ̀tá láìnídìí lágbára, àwọn tí ó kórìíra mi láìtọ́ sì pọ̀. Àwọn tí ń fi ibi san oore fún mi ní ń gbógun tì mí, nítorí pé rere ni mò ń ṣe. OLUWA, má kọ̀ mí sílẹ̀, Ọlọrun mi, má jìnnà sí mi. Yára wá ràn mí lọ́wọ́, OLUWA, ìgbàlà mi. Mo ní, “Èmi óo máa ṣọ́ra, kí n má baà fi ahọ́n mi dẹ́ṣẹ̀; n óo kó ẹnu mi ní ìjánu, níwọ̀n ìgbà tí àwọn eniyan burúkú bá wà nítòsí.” Mo dákẹ́, n ò sọ nǹkankan; n ò tilẹ̀ dá sí ọ̀rọ̀ rere pàápàá; sibẹ ìpọ́njú mi ń pọ̀ sí i ìdààmú dé bá ọkàn mi. Bí mo ti ń ronú, ọkàn mi dàrú; mo bá sọ̀rọ̀ jáde, mo ní: “OLUWA, jẹ́ kí n mọ òpin ayé mi, ati ìwọ̀nba ọjọ́ ayé mi, kí n lè mọ̀ pé ayé mi ń sáré kọjá lọ.” Wò ó, o ti ṣe ọjọ́ mi ní ìwọ̀n ìbú àtẹ́lẹwọ́ mélòó kan, ọjọ́ ayé mi kò sì tó nǹkankan ní ojú rẹ; dájúdájú, ọmọ eniyan dàbí afẹ́fẹ́ lásán. Dájúdájú, eniyan ń káàkiri bí òjìji, asán sì ni gbogbo làálàá rẹ̀; eniyan a máa kó ọrọ̀ jọ ṣá, láìmọ ẹni tí yóo kó o lọ. Wàyí ò, OLUWA, kí ló kù tí mo gbójú lé? Ìwọ ni mo fẹ̀yìn tì. Gbà mí ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ìrékọjá mi; má sọ mí di ẹni ẹ̀gàn lójú àwọn òmùgọ̀. Mo dákẹ́, n kò ya ẹnu mi; nítorí pé ìwọ ni o ṣe é. Dáwọ́ ẹgba rẹ dúró lára mi, mo ti fẹ́rẹ̀ kú nítorí ìyà tí o fi ń jẹ mí. Nígbà tí o bá jẹ eniyan níyà pẹlu ìbáwí nítorí ẹ̀ṣẹ̀, ìwọ á ba ohun tí ó ṣọ̀wọ́n fún un jẹ́ bíi kòkòrò aṣọ. Dájúdájú, afẹ́fẹ́ lásán ni eniyan. “OLUWA, gbọ́ adura mi, tẹ́tí sí igbe mi, má dágunlá sí ẹkún mi, nítorí pé àlejò rẹ, tí ń rékọjá lọ ni mo jẹ́; àjèjì sì ni mí, bíi gbogbo àwọn baba mi. Mú ojú ìbáwí kúrò lára mi, kí inú mi lè dùn kí n tó kọjá lọ; àní, kí n tó ṣe aláìsí.” Sùúrù ni mo fi dúró de OLUWA, ó dẹ etí sí mi, ó sì gbọ́ igbe mi. Ó fà mí jáde láti inú ọ̀gbun ìparun, láti inú kòtò tí ó kún fún ẹrọ̀fọ̀; ó gbé mi kalẹ̀ lórí àpáta, ó sì fi ẹsẹ̀ mi tẹlẹ̀. Ó fi orin titun sí mi lẹ́nu, àní, orin ìyìn sí Ọlọrun wa. Ọ̀pọ̀ yóo rí i, ẹ̀rù óo bà wọ́n, wọn óo sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni náà, tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé OLUWA, tí kò bá àwọn onigbeeraga rìn, àwọn tí wọn ti ṣìnà lọ sọ́dọ̀ àwọn oriṣa. OLUWA, Ọlọrun mi, o ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu fún wa, o sì ti ro ọ̀pọ̀ èrò rere kàn wá. Kò sí ẹni tí a lè fi wé ọ; bí mo bá ní kí n máa polongo ohun tí o ṣe, kí n máa ròyìn wọn, wọ́n ju ohun tí eniyan lè kà lọ. O ò fẹ́ ẹbọ, bẹ́ẹ̀ ni o ò fẹ́ ọrẹ, ṣugbọn o là mí ní etí; o ò bèèrè ẹbọ sísun tabi ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Nígbà náà ni mo wí pé, “Wò ó, mo dé; a ti kọ nípa mi sinu ìwé pé: mo gbádùn láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọrun mi; mo sì ń pa òfin rẹ mọ́ ninu ọkàn mi.” Mo ti ròyìn òdodo ninu àwùjọ ńlá. Wò ó, OLUWA n kò pa ẹnu mi mọ́, gẹ́gẹ́ bí o ti mọ̀. Èmi kò fi ìròyìn ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà rẹ pamọ́. Mo sọ̀rọ̀ òtítọ́ ati ìgbàlà rẹ; n kò dákẹ́ lẹ́nu nípa òtítọ́ ati ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, ninu àwùjọ ńlá. Má dáwọ́ àánú rẹ dúró lórí mi, OLUWA, sì jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ rẹ máa pa mí mọ́. Nítorí pé àìmọye ìdààmú ló yí mi ká, ọwọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi ti tẹ̀ mí, tóbẹ́ẹ̀ tí n kò ríran. Wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ, ọkàn mi ti dàrú. OLUWA, dákun gbà mi; yára, OLUWA, ràn mí lọ́wọ́. Jẹ́ kí ojú ti gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ gba ẹ̀mí mi, kí ìdàrúdàpọ̀ bá gbogbo wọn patapata, jẹ́ kí á lé àwọn tí ń wá ìpalára mi pada sẹ́yìn, kí wọ́n sì tẹ́. Jẹ́ kí jìnnìjìnnì bò wọ́n, kí wọ́n sì gba èrè ìtìjú, àní, àwọn tí ń ṣe jàgínní mi. Kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ máa yọ̀, kí inú wọn sì máa dùn nítorí rẹ; kí àwọn tí ó fẹ́ràn ìgbàlà rẹ máa wí nígbà gbogbo pé, “OLUWA tóbi!” Ní tèmi, olùpọ́njú ati aláìní ni mí; ṣugbọn Oluwa kò gbàgbé mi. Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ ati olùgbàlà mi, má pẹ́, Ọlọrun mi. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ń ro ti àwọn aláìní: OLUWA yóo gbà á ní ọjọ́ ìpọ́njú. OLUWA yóo máa ṣọ́ ọ, yóo sì dá a sí. Yóo ní ayọ̀ ní ilẹ̀ náà; OLUWA kò ní fi í lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́. Nígbà tí ó bá wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn, OLUWA yóo fún un lókun; ní àkókò àìlera OLUWA yóo wo gbogbo àrùn rẹ̀ sàn. Mo ní, “OLUWA, ṣàánú mi kí o sì wò mí sàn; mo ti ṣẹ̀ ọ́.” Àwọn ọ̀tá mi ń ro ibi sí mi, wọ́n ń wí pé, “Nígbà wo ni yóo kú, tí orúkọ rẹ̀ yóo parẹ́?” Tí ọ̀kan bá wá bẹ̀ mí wò, ọ̀rọ̀ tí kò lórí, tí kò nídìí ni yóo máa sọ; bẹ́ẹ̀ ni ninu ọkàn rẹ̀, èrò ibi ni yóo máa gbà. Nígbà tí ó bá jáde, yóo máa rò mí kiri. Gbogbo àwọn tí ó kórìíra mi jọ ń sọ̀rọ̀ wújẹ́wújẹ́ nípa mi; ohun tó burú jùlọ ni wọ́n ń rò sí mi. Wọ́n ń wí pé, “Àìsàn burúkú ti gbé e dálẹ̀; kò ní dìde mọ́ níbi tí ó dùbúlẹ̀ sí.” Àní ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi tí mo gbẹ́kẹ̀lé, tí ó ń jẹun nílé mi, ó ti kẹ̀yìn sí mí. Ṣugbọn, OLUWA, ṣàánú mi; gbé mi dìde, kí n lè san ẹ̀san fún un. Kí n lè mọ̀ pé o fẹ́ràn mi, nígbà tí ọ̀tá kò bá borí mi. O ti gbé mi ró nítorí ìwà pípé mi, o sì fi ẹsẹ̀ mi múlẹ̀ níwájú rẹ títí lae. Ìyìn ni fún OLUWA, Ọlọrun Israẹli, lae ati laelae. Amin! Amin! Bí ọkàn àgbọ̀nrín tií máa fà sí odò tí omi rẹ̀ tutù, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi ń fà sí ọ, Ọlọrun. Òùngbẹ Ọlọrun ń gbẹ ọkàn mi, àní, òùngbẹ Ọlọrun alààyè. Nígbà wo ni n óo lọ, tí n óo tún bá Ọlọrun pàdé? Omijé ni mo fi ń ṣe oúnjẹ jẹ tọ̀sán-tòru, nígbà tí wọn ń bi mí lemọ́lemọ́ pé, “Níbo ni Ọlọrun rẹ wà?” Àwọn nǹkan wọnyi ni mò ń ranti, bí mo ti ń tú ẹ̀dùn ọkàn mi jáde: bí mo ṣe máa ń bá ogunlọ́gọ̀ eniyan rìn, tí mò ń ṣáájú wọn, bí a bá ti ń rìn lọ́wọ̀ọ̀wọ́ lọ sí ilé Ọlọrun; pẹlu ìhó ayọ̀ ati orin ọpẹ́, láàrin ogunlọ́gọ̀ eniyan tí ń ṣe àjọ̀dún. Ìwọ ọkàn mi, kí ló dé tí o fi rẹ̀wẹ̀sì? Kí ló dé tí ara rẹ kò fi balẹ̀ ninu mi? Gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ọlọrun, nítorí pé n óo tún yìn ín, olùrànlọ́wọ́ mi ati Ọlọrun mi. Ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn mi, nítorí náà mo ranti rẹ láti òkè Herimoni, ati láti òkè Misari, wá sí agbègbè odò Jọdani, ìbànújẹ́ ń já lura wọn, ìdààmú sì ń dà gììrì, wọ́n bò mí mọ́lẹ̀ bí ìgbì omi òkun. Ní ọ̀sán, OLUWA fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn, ní òru, orin rẹ̀ gba ẹnu mi, àní, adura sí Ọlọrun ìyè mi. Mo bi Ọlọrun, àpáta mi pé, “Kí ló dé tí o fi gbàgbé mi? Kí ló dé tí mò ń ṣọ̀fọ̀ kiri nítorí ìnilára ọ̀tá?” Bí ọgbẹ́ aṣekúpani ni ẹ̀gàn àwọn ọ̀tá mi rí lára mi, nígbà tí wọn ń bi mí lemọ́lemọ́ pé, “Níbo ni Ọlọrun rẹ wà?” Ìwọ ọkàn mi, kí ló dé tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì? Kí ló dé tí ara rẹ kò fi balẹ̀ ninu mi? Gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ọlọrun; nítorí pé n óo tún yìn ín, olùrànlọ́wọ́ mi ati Ọlọrun mi. Dá mi láre, Ọlọrun, kí o sì gbèjà mi, lọ́dọ̀ àwọn tí kò mọ̀ Ọ́; gbà mí lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́tàn ati alaiṣootọ. Nítorí ìwọ ni Ọlọrun tí mo sá di. Kí ló dé tí o fi ta mí nù? Kí ló dé tí mo fi ń ṣọ̀fọ̀ kiri nítorí ìnilára ọ̀tá? Rán ìmọ́lẹ̀ rẹ ati òtítọ́ rẹ jáde, jẹ́ kí wọ́n máa tọ́ mi sọ́nà; jẹ́ kí wọ́n mú mi wá sí orí òkè mímọ́ rẹ, ati ibùgbé rẹ. Nígbà náà ni n óo lọ sí ibi pẹpẹ Ọlọrun, àní, sọ́dọ̀ Ọlọrun, ayọ̀ ńlá mi. Èmi óo sì yìn ọ́ pẹlu hapu, Ọlọrun, Ọlọrun mi. Ìwọ ọkàn mi, kí ló dé tí o fi rẹ̀wẹ̀sì? Kí ló dé tí ara rẹ kò fi balẹ̀ ninu mi? Gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ọlọrun; nítorí pé n óo tún yìn ín, olùrànlọ́wọ́ mi ati Ọlọrun mi. Ọlọrun, a ti fi etí wa gbọ́, àwọn baba wa sì ti sọ fún wa, nípa àwọn ohun tí o ṣe nígbà ayé wọn, àní, ní ayé àtijọ́: Ìwọ ni o fi ọwọ́ ara rẹ lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde fún wọn, tí o sì fi ẹsẹ̀ àwọn baba wa múlẹ̀; o fi ìyà jẹ àwọn orílẹ̀-èdè náà, o sì jẹ́ kí ó dára fún àwọn baba wa. Nítorí pé kì í ṣe idà wọn ni wọ́n fi gba ilẹ̀ náà, kì í ṣe agbára wọn ni wọ́n fi ṣẹgun; agbára rẹ ni; àní, agbára ọwọ́ ọ̀tún rẹ, ati ojurere rẹ; nítorí pé inú rẹ dùn sí wọn. Ìwọ ni Ọba mi ati Ọlọrun mi; ìwọ ni o fi àṣẹ sí i pé kí Jakọbu ó ṣẹgun. Nípa agbára rẹ ni a fi bi àwọn ọ̀tá wa sẹ́yìn, orúkọ rẹ ni a fi tẹ àwọn tí ó gbógun tì wá mọ́lẹ̀. Nítorí pé kì í ṣe ọrun mi ni mo gbẹ́kẹ̀lé; idà mi kò sì le gbà mí. Ṣugbọn ìwọ ni o gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, o sì dójú ti àwọn tí ó kórìíra wa. Ìwọ Ọlọrun ni a fi ń yangàn nígbà gbogbo; a óo sì máa fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ títí lae. Sibẹ, o ti ta wá nù o sì ti rẹ̀ wá sílẹ̀, o ò sì bá àwọn ọmọ ogun wa jáde lọ sójú ogun mọ́. O ti mú kí á sá fún àwọn ọ̀tá wa lójú ogun; àwọn tí ó kórìíra wa sì fi ẹrù wa ṣe ìkógun. O ti ṣe wá bí aguntan lọ́wọ́ alápatà, o sì ti fọ́n wa káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè. O ti ta àwọn eniyan rẹ lọ́pọ̀, o ò sì jẹ èrè kankan lórí wọn. O ti sọ wá di ẹni ẹ̀gàn lọ́wọ́ àwọn aládùúgbò wa; a di ẹni ẹ̀sín ati ẹni yẹ̀yẹ́ lọ́dọ̀ àwọn tí ó yí wa ká. O sọ wá di ẹni àmúpòwe láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, ati ẹni yẹ̀yẹ́ láàrin gbogbo ayé. Àbùkù mi wà lára mi tọ̀sán-tòru, ìtìjú sì ti bò mí. Ọ̀rọ̀ àwọn apẹ̀gàn ati apeni-níjà ṣẹ mọ́ mi lára, lójú àwọn ọ̀tá mi ati àwọn tí ó fẹ́ gbẹ̀san. Gbogbo nǹkan yìí ló ṣẹlẹ̀ sí wa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò gbàgbé rẹ, bẹ́ẹ̀ ni a kò yẹ majẹmu rẹ. Ọkàn wa kò pada lẹ́yìn rẹ, bẹ́ẹ̀ ni a kò yẹsẹ̀ kúrò ninu ìlànà rẹ, sibẹ o fọ́ wa túútúú fún ìjẹ àwọn ẹranko, o sì fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀. Bí ó bá jẹ́ pé a gbàgbé orúkọ Ọlọrun wa, tabi tí a bá bọ oriṣa, ṣebí Ọlọrun ìbá ti mọ̀? Nítorí òun ni olùmọ̀ràn ọkàn. Ṣugbọn nítorí tìrẹ ni wọ́n fi ń pa wá tọ̀sán-tòru, tí a kà wá sí aguntan lọ́wọ́ alápatà. Para dà, OLUWA, kí ló dé tí o fi ń sùn? Jí gìrì! Má ta wá nù títí lae. Kí ló dé tí o fi ń fi ojú pamọ́? Kí ló dé tí o fi gbàgbé ìpọ́njú ati ìnira wa? Nítorí pé àwọn ọ̀tá ti tẹ̀ wá mọ́lẹ̀; àyà wa sì lẹ̀ mọ́lẹ̀ típẹ́típẹ́. Gbéra nílẹ̀, kí o ràn wá lọ́wọ́! Gbà wá sílẹ̀ nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀. Èrò rere kan ń gbé mi lọ́kàn, mò ń kọ orin mi fún ọba ahọ́n mi dàbí gègé akọ̀wé tó mọṣẹ́. Ìwọ ni o dára jùlọ láàrin àwọn ọkunrin; ọ̀rọ̀ dùn lẹ́nu rẹ, nítorí náà Ọlọrun ti bukun ọ títí ayé. Sán idà rẹ mọ́ ìdí, ìwọ alágbára, ninu ògo ati ọlá ńlá rẹ. Máa gun ẹṣin ìṣẹ́gun lọ ninu ọlá ńlá rẹ, máa jà fún òtítọ́ ati ẹ̀tọ́, kí ọwọ́ ọ̀tún rẹ fún ọ ní ìṣẹ́gun ńlá. Àwọn ọfà rẹ mú, wọ́n gún àwọn ọ̀tá ọba lọ́kàn, àwọn eniyan ń wó lulẹ̀ níwájú rẹ. Ìjọba tí Ọlọrun fún ọ wà lae ati laelae. Ọ̀pá àṣẹ rẹ, ọ̀pá àṣẹ ẹ̀tọ́ ni. O fẹ́ràn òdodo, o sì kórìíra ìwà ìkà nítorí náà ni Ọlọrun, àní Ọlọrun rẹ, ṣe fi àmì òróró yàn ọ́. Àmì òróró ayọ̀ ni ó fi gbé ọ ga ju àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ lọ. Aṣọ rẹ kún fún òórùn oríṣìíríṣìí turari, láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ ni wọ́n tí ń fi ohun èlò ìkọrin olókùn dá ọ lára yá. Àwọn ọmọ ọba wà lára àwọn obinrin inú àgbàlá rẹ, ayaba dúró ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ, ó fi ojúlówó wúrà ṣe ọ̀ṣọ́ sára. Gbọ́, ìwọ ọmọbinrin, ronú kí o sì tẹ́tí sílẹ̀, gbàgbé àwọn eniyan rẹ ati ilé baba rẹ; ẹwà rẹ yóo sì mú ọ wu ọba; òun ni oluwa rẹ, nítorí náà bu ọlá fún un. Àwọn ará Tire yóo máa fi ẹ̀bùn wá ojurere rẹ, àní, àwọn eniyan tí wọ́n ní ọrọ̀ jùlọ. Yóo máa wá ojurere rẹ, pẹlu oríṣìíríṣìí ọrọ̀. Ọmọ ọbabinrin fi aṣọ wúrà ṣọ̀ṣọ́ jìngbìnnì ninu yàrá rẹ̀, ó wọ aṣọ aláràbarà, a mú un lọ sọ́dọ̀ ọba, pẹlu àwọn wundia ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọn ń sìn ín lọ. Pẹlu ayọ̀ ati inú dídùn ni a fi ń mú wọn lọ, bí wọ́n ṣe ń wọ ààfin ọba. Àwọn ọmọkunrin rẹ ni yóo rọ́pò àwọn baba rẹ; o óo fi wọ́n jọba káàkiri gbogbo ayé. N óo mú kí á máa ki oríkì rẹ láti ìran dé ìran; nítorí náà àwọn eniyan yóo máa yìn ọ́ lae ati laelae. Ọlọrun ni ààbò ati agbára wa, olùrànlọ́wọ́ tí ó wà nítòsí nígbà gbogbo, ní ìgbà ìpọ́njú. Nítorí náà ẹ̀rù kò ní bà wá bí ayé tilẹ̀ ṣídìí, bí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ṣípò pada, tí wọ́n bọ́ sinu òkun; bí omi òkun tilẹ̀ ń hó, tí ó sì ń ru, tí àwọn òkè ńlá sì ń mì tìtì nítorí agbára ríru rẹ̀. Odò kan wà tí omi rẹ̀ ń mú inú ìlú Ọlọrun dùn, ìlú yìí ni ibùgbé mímọ́ Ọ̀gá Ògo. Ọlọrun wà láàrin rẹ̀, kò ní tú bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣí kúrò; Ọlọrun yóo ràn án lọ́wọ́ ní òwúrọ̀ kutukutu. Inú àwọn orílẹ̀-èdè ń ru, àwọn ìjọba ayé ń gbọ̀n; OLUWA fọhùn, ayé sì yọ́. OLUWA àwọn ọmọ ogun wà pẹlu wa; Ọlọrun Jakọbu ni ààbò wa. Ẹ wá wo iṣẹ́ OLUWA, irú iṣẹ́ ribiribi tí ó ṣe láyé. Ó dáwọ́ ogun dúró ní gbogbo ayé, ó ṣẹ́ ọrun, ó rún ọ̀kọ̀, ó dáná sun kẹ̀kẹ́ ogun. “Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ni Ọlọrun. A gbé mi ga láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, a gbé mi ga ní ayé.” OLUWA àwọn ọmọ ogun wà pẹlu wa, Ọlọrun Jakọbu ni ààbò wa. Ẹ pàtẹ́wọ́, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè; ẹ kọ orin ayọ̀, ẹ hó sí Ọlọrun. Nítorí pé ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ni OLUWA, Ọ̀gá Ògo, Ọba ńlá lórí gbogbo ayé. Ó tẹ àwọn orílẹ̀-èdè lórí ba fún wa, ó sì sọ àwọn orílẹ̀-èdè di àtẹ̀mọ́lẹ̀ fún wa. Òun ni ó yan ilẹ̀ ìní wa fún wa, èyí tí àwọn ọmọ Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀, fi ń yangàn. A ti gbé Ọlọrun ga pẹlu ìhó ayọ̀, a ti gbé OLUWA ga pẹlu ìró fèrè. Ẹ kọ orin ìyìn sí Ọlọrun, ẹ kọ orin ìyìn; Ẹ kọ orin ìyìn sí Ọba wa, ẹ kọ orin ìyìn! Nítorí Ọlọrun ni Ọba gbogbo ayé; Ẹ fi gbogbo ohun èlò ìkọrin kọ orin ìyìn! Ọlọrun jọba lórí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; Ó gúnwà lórí ìtẹ́ mímọ́ rẹ̀. Àwọn ìjòyè orílẹ̀-èdè kó ara wọn jọ pẹlu àwọn eniyan Ọlọrun Abrahamu. Ọlọrun ni aláṣẹ gbogbo ayé; òun ni ọlọ́lá jùlọ! OLUWA tóbi, ó sì yẹ kí á máa yìn ín lọpọlọpọ ní ìlú Ọlọrun wa. Òkè mímọ́ rẹ̀, tí ó ga, tí ó sì lẹ́wà, ni ayọ̀ gbogbo ayé. Òkè Sioni, ní àríwá, lọ́nà jíjìn réré, ìlú ọba ńlá. Ninu ilé ìṣọ́ ìlú náà, Ọlọrun ti fi ara rẹ̀ hàn bí ibi ìsádi. Wò ó! Àwọn ọba kó ara wọn jọ; wọ́n jùmọ̀ gbógun tì í. Nígbà tí wọ́n fojú kàn án, ẹnu yà wọ́n, ìpayà mú wọn, wọ́n sì sá; ìwárìrì mú wọn níbẹ̀; ìrora sì bá wọn bí obinrin tí ń rọbí. Ó fọ́ wọn bí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn tií fọ́ ọkọ̀ Taṣiṣi. Bí a ti gbọ́, bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí, ní ìlú OLUWA àwọn ọmọ ogun, ní ìlú Ọlọrun wa: Ọlọrun fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí lae. Ninu tẹmpili rẹ, Ọlọrun, à ń ṣe àṣàrò lórí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀. Ọlọrun, ìyìn rẹ tàn ká, bí orúkọ rẹ ṣe tàn dé òpin ayé, iṣẹ́ rere kún ọwọ́ rẹ. Jẹ́ kí inú òkè Sioni kí ó dùn, kí gbogbo Juda sì máa yọ̀ nítorí ìdájọ́ rẹ. Ẹ rìn yí Sioni po; ẹ yí i ká; ẹ ka àwọn ilé ìṣọ́ rẹ̀; ẹ ṣàkíyèsí odi rẹ̀; ẹ wọ inú gbogbo ilé ìṣọ́ rẹ̀ lọ, kí ẹ lè ròyìn fún ìran tí ń bọ̀ pe: “Ọlọrun yìí ni Ọlọrun wa, lae ati laelae. Òun ni yóo máa ṣe amọ̀nà wa títí lae.” Ẹ gbọ́, gbogbo orílẹ̀-èdè! Ẹ dẹtí sílẹ̀, gbogbo aráyé, ati mẹ̀kúnnù àtọlọ́lá, àtolówó ati talaka! Ẹnu mi yóo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n; àṣàrò ọkàn mi yóo sì jẹ́ ti òye. N óo tẹ́tí sílẹ̀ sí òwe; n óo sì fi hapu túmọ̀ rẹ̀. Kí ló dé tí n óo fi bẹ̀rù ní àkókò ìyọnu, nígbà tí iṣẹ́ ibi àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi bá yí mi ká, àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọn, tí wọ́n sì ń yangàn nítorí wọ́n ní ọrọ̀ pupọ? Dájúdájú, kò sí ẹni tí ó le ra ara rẹ̀ pada, tabi tí ó lè san owó ìràpadà ẹ̀mí rẹ̀ fún Ọlọrun; nítorí pé ẹ̀mí eniyan níye lórí pupọ. Kò sí iye tí eniyan ní tí ó le kájú rẹ̀, tí eniyan lè máa fi wà láàyè títí lae, kí ó má fojú ba ikú. Yóo rí i pé ikú a máa pa ọlọ́gbọ́n, òmùgọ̀ ati òpè a sì máa rọ̀run; wọn a sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn. Ibojì wọn ni ilé wọn títí lae, ibẹ̀ ni ibùgbé wọn títí ayérayé, wọn ìbáà tilẹ̀ ní ilẹ̀ ti ara wọn. Eniyan kò lè máa gbé ninu ọlá rẹ̀ títí ayé, bí ẹranko tíí kú, ni òun náà óo kú. Ìpín àwọn tí ó ní igbẹkẹle asán nìyí, òun sì ni èrè àwọn tí ọrọ̀ wọn tẹ́ lọ́rùn. Ikú ni ìpín wọn bí àgùntàn lásánlàsàn, ikú ni yóo máa ṣe olùṣọ́ wọn; ibojì ni wọ́n sì ń lọ tààrà. Wọn yóo jẹrà, ìrísí wọn óo sì parẹ́, Àwọn olódodo yóo jọba lórí wọn ní òwúrọ̀, ibojì ni yóo sì máa jẹ́ ilé wọn. Ṣugbọn Ọlọrun yóo ra ẹ̀mí mi pada lọ́wọ́ ikú nítorí pé yóo gbà mí. Má ba ara jẹ́ bí ẹnìkan bá di olówó, tí ọrọ̀ rẹ̀ ń pọ̀ sí i. Nítorí pé ní ọjọ́ tí ó bá kú, kò ní mú ohunkohun lọ́wọ́ lọ; dúkìá rẹ̀ kò sì ní bá a wọ ibojì. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà tí ó wà láàyè, ó rò pé Ọlọrun bukun òun, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé a máa yin eniyan nígbà tí nǹkan bá ń dára fún un, yóo kú bí àwọn baba ńlá rẹ̀ ti kú, kò sì ní fojú kan ìmọ́lẹ̀ mọ́. Eniyan kò lè máa gbé inú ọlá rẹ̀ títí ayé; bí ẹranko tíí kú, ni òun náà óo ku. OLUWA, Ọlọrun Alágbára ti sọ̀rọ̀: ó ké sí gbogbo ayé láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn. Ọlọrun yọ bí ọjọ́ láti Sioni, ìlú tó dára, tó lẹ́wà. Ọlọrun wa ń bọ̀, kò dákẹ́: iná ajónirun ń jó níwájú rẹ̀; ìjì líle sì ń jà yí i ká. Ó ké sí ọ̀run lókè; ó pe ayé pẹlu láti gbọ́ ìdájọ́ tí yóo ṣe fún àwọn eniyan rẹ̀. Ó ní, “Ẹ kó àwọn olùfọkànsìn mi jọ sọ́dọ̀ mi, àwọn tí wọ́n ti fi ẹbọ bá mi dá majẹmu!” Ojú ọ̀run ń kéde òdodo rẹ̀ pé Ọlọrun ni onídàájọ́. “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan mi, n óo sọ̀rọ̀, Israẹli, n óo takò yín. Èmi ni Ọlọrun, Ọlọrun yín. N kò ba yín wí nítorí ẹbọ rírú; nígbà gbogbo ni ẹ̀ ń rú ẹbọ sísun sí mi. N kò ní gba akọ mààlúù lọ́wọ́ yín, tabi òbúkọ láti agbo ẹran yín. Nítorí èmi ni mo ni gbogbo ẹran inú igbó, tèmi sì ni gbogbo mààlúù tó wà lórí ẹgbẹrun òkè. Gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ni mo mọ̀, tèmi sì ni gbogbo nǹkan tí ń rìn ninu pápá. “Bí ebi bá tilẹ̀ pa mí, ẹ̀yin kọ́ ni n óo sọ fún, nítorí èmi ni mo ni gbogbo ayé ati àwọn nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀. Ṣé èmi a máa jẹ ẹran akọ mààlúù? Àbí mà máa mu ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́? Ọpẹ́ ni kí ẹ fi rúbọ sí Ọlọrun, kí ẹ sì máa san ẹ̀jẹ́ yín fún Ọ̀gá Ògo. Ẹ ké pè mí ní ọjọ́ ìṣòro; n óo gbà yín, ẹ óo sì yìn mí lógo.” Ṣugbọn Ọlọrun bi àwọn eniyan burúkú pé, “Ẹ̀tọ́ wo ni ẹ níláti máa ka àwọn òfin mi, tabi láti máa mú ẹnu ba ìlànà mi? Nítorí ẹ kórìíra ẹ̀kọ́; ẹ sì ti ta àṣẹ mi nù. Tí ẹ bá rí olè, ẹ̀yin pẹlu rẹ̀ a dọ̀rẹ́; ẹ sì ń bá àwọn panṣaga kẹ́gbẹ́. “Ọ̀rọ̀ ibi dùn lẹ́nu yín pupọ; ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn sì yọ̀ létè yín. Ẹ̀ ń jókòó sọ̀rọ̀ arakunrin yín níbi: ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ nípa ọmọ ìyá yín. Gbogbo nǹkan wọnyi ni ẹ ti ṣe tí mo sì dákẹ́; ẹ wá ń rò ninu yín pé, èmi yín rí bákan náà. Ṣugbọn nisinsinyii mò ń ba yín wí, mo sì ń fi ẹ̀sùn kàn yín. “Nítorí náà, ẹ fi èyí lékàn, ẹ̀yin tí ẹ gbàgbé Ọlọrun, kí n má baà fà yín ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, kò sì ní sí ẹni tí yóo gbà yín kalẹ̀. Ẹni tí ó bá mu ọpẹ́ wá, tí ó fi rúbọ sí mi, ni ó bu ọlá fún mi; ẹni tí ó bá sì rìn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ ni èmi Ọlọrun yóo gbà là.” Ṣàánú mi, Ọlọrun, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀; nítorí ọ̀pọ̀ àánú rẹ pa ẹ̀ṣẹ̀ mi rẹ́. Wẹ̀ mí mọ́ kúrò ninu àìdára mi, kí o sì wẹ̀ mí kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ mi! Nítorí mo mọ ibi tí mo ti ṣẹ̀, nígbà gbogbo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi sì wà níwájú mi. Ìwọ nìkan, àní, ìwọ nìkan ṣoṣo ni mo ṣẹ̀, tí mo ṣe ohun tí ó burú lójú rẹ, kí ẹjọ́ rẹ lè tọ́ nígbà tí o bá ń dájọ́, kí ọkàn rẹ lè mọ́ nígbà tí o bá ń ṣe ìdájọ́. Dájúdájú, ninu àìdára ni a bí mi, ninu ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mi sì lóyún mi. O fẹ́ràn òtítọ́ inú; nítorí náà, kọ́ mi lọ́gbọ́n ní kọ́lọ́fín ọkàn mi. Fi ewé hisopu fọ̀ mí, n óo sì mọ́; wẹ̀ mí, n óo sì funfun ju ẹ̀gbọ̀n òwú lọ. Fún mi ní ayọ̀ ati inú dídùn, kí gbogbo egungun mi tí ó ti rún lè máa yọ̀. Mójú kúrò lára ẹ̀ṣẹ̀ mi, kí o sì pa gbogbo àìdára mi rẹ́. Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọrun, kí o sì fi ẹ̀mí ọ̀tun ati ẹ̀mí ìṣòótọ́ sí mi lọ́kàn. Má ta mí nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ, má sì gba Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ lọ́wọ́ mi. Dá ayọ̀ ìgbàlà rẹ pada fún mi, kí o sì fi ẹ̀mí àtiṣe ìfẹ́ rẹ gbé mi ró. Nígbà náà ni n óo máa kọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ọ̀nà rẹ, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo sì máa yipada sí ọ. Gbà mí lọ́wọ́ ẹ̀bi ìpànìyàn, Ọlọrun, ìwọ Ọlọrun, Olùgbàlà mi, n óo sì máa fi orin kéde iṣẹ́ rere rẹ. OLUWA, là mí ní ohùn, n óo sì máa ròyìn iṣẹ́ ńlá rẹ. Bí ó bá jẹ́ pé o fẹ́ ẹbọ ni, ǹ bá mú wá fún ọ; ṣugbọn o ò tilẹ̀ fẹ́ ẹbọ sísun. Ẹbọ tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ ìwọ Ọlọrun ni ẹ̀mí ìròbìnújẹ́, ọkàn ìròbìnújẹ́ ati ìrònúpìwàdà ni ìwọ kì yóo gàn. Jẹ́ kí ó dára fún Sioni ninu ìdùnnú rẹ; tún odi Jerusalẹmu mọ. Nígbà náà ni inú rẹ yóo dùn sí ẹbọ tí ó tọ́, ẹbọ sísun, ati ẹbọ tí a sun lódidi; nígbà náà ni a óo fi akọ mààlúù rúbọ lórí pẹpẹ rẹ. Ìwọ alágbára, kí ló dé tí o fi ń fọ́nnu, kí ló dé tí ò ń fọ́nnu tọ̀sán-tòru? Ẹni ìtìjú ni ọ́ lójú Ọlọrun. Ò ń pète ìparun; ẹnu rẹ dàbí abẹ tí ó mú, ìwọ alárèékérekè. O fẹ́ràn ibi ju ire lọ, o sì fẹ́ràn irọ́ ju òtítọ́ lọ. O fẹ́ràn gbogbo ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́, Ìwọ ẹlẹ́tàn! Nítòótọ́ Ọlọrun óo bá ọ kanlẹ̀, yóo gbá ọ mú, yóo sì fà ọ́ já kúrò ninu ilé rẹ; yóo fà ọ́ tu kúrò lórí ilẹ̀ alààyè. Nígbà tí àwọn olódodo bá rí i, ẹ̀rù óo bà wọ́n, wọn óo fi rẹ́rìn-ín, wọn óo sì wí pé, “Wo ẹni tí ó kọ̀, tí kò fi Ọlọrun ṣe ààbò rẹ̀, ṣugbọn ó gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ tí ó pọ̀, ati jamba tí ó ń ta fún ẹlòmíràn.” Ṣugbọn èmi dàbí igi olifi tútù tí ń dàgbà ninu ilé OLUWA, mo gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọrun tí kì í yẹ̀, lae ati laelae. N óo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ títí lae, nítorí ohun tí o ṣe, n óo máa kéde orúkọ rẹ níwájú àwọn olùfọkànsìn rẹ, nítorí pé ó dára bẹ́ẹ̀. Òmùgọ̀ sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé, “Kò sí Ọlọrun.” Wọ́n bàjẹ́, ohun ìríra ni wọ́n ń ṣe, kò sì sí ẹnìkan ninu wọn tí ń ṣe rere. Ọlọrun bojú wo àwọn ọmọ eniyan láti ọ̀run wá, ó ń wò ó bí àwọn kan bá wà tí òye yé, àní, bí àwọn kan bá wà tí ń wá Ọlọrun. Gbogbo wọn ni ó ti yapa; tí wọn sì ti bàjẹ́, kò sí ẹnìkan tí ń ṣe rere, kò sí, bó tilẹ̀ jẹ́ ẹnìkan ṣoṣo. Ṣé gbogbo àwọn aṣebi kò gbọ́n ni? Àwọn tí ń jẹ eniyan mi bí ẹni jẹun, àní àwọn tí kì í ké pe Ọlọrun. Ẹ wò wọ́n, bí wọ́n ṣe wà ninu ẹ̀rù ńlá, ẹ̀rù tí kò tíì sí irú rẹ̀ rí! Nítorí Ọlọrun yóo fọ́n egungun àwọn ọ̀tá rẹ̀ ká; ojú óo tì wọ́n, nítorí Ọlọrun ti kọ̀ wọ́n. Ìbá ti dára tó, kí ìgbàlà Israẹli ti Sioni wá! Nígbà tí Ọlọrun bá dá ire àwọn eniyan rẹ̀ pada, Jakọbu yóo yọ̀, inú Israẹli yóo sì dùn. Fi agbára orúkọ rẹ gbà mí, Ọlọrun, fi ipá rẹ dá mi láre. Gbọ́ adura mi, Ọlọrun; tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi. Nítorí pé àwọn agbéraga dìde sí mi, àwọn ìkà, aláìláàánú sì ń lépa ẹ̀mí mi; wọn kò bìkítà fún Ọlọrun. Ṣugbọn Ọlọrun ni olùrànlọ́wọ́ mi, OLUWA ni ó gbé ẹ̀mí mi ró. Yóo san ẹ̀san ibi fún àwọn ọ̀tá mi; OLUWA, nítorí òtítọ́ rẹ, pa wọ́n run. N óo rú ẹbọ ọrẹ àtinúwá sí ọ, n óo máa yin orúkọ rẹ, OLUWA, nítorí pé ó dára bẹ́ẹ̀. O ti yọ mí ninu gbogbo ìṣòro mi, mo sì ti fi ojú mi rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi. Tẹ́tí sí adura mi, Ọlọrun, má sì fara pamọ́ nígbà tí mo bá ń bẹ̀bẹ̀. Fetí sí mi, kí o sì dá mi lóhùn; ìṣòro ti borí mi. Ìhàlẹ̀ ọ̀tá bà mí ninu jẹ́, nítorí ìnilára àwọn eniyan burúkú; wọ́n kó ìyọnu bá mi, wọ́n ń bínú mi, inú wọn sì dùn láti máa bá mi ṣọ̀tá. Ọkàn mi wà ninu ìrora, ìpayà ikú ti dé bá mi. Ẹ̀rù ati ìwárìrì dà bò mí, ìpayà sì bò mí mọ́lẹ̀. Mo ní, “Èmi ìbá ní ìyẹ́ bí àdàbà! Ǹ bá fò lọ, ǹ bá lọ sinmi. Áà! Ǹ bá lọ jìnnà réré, kí n lọ máa gbé inú ijù; ǹ bá yára lọ wá ibi ààbò kúrò lọ́wọ́ afẹ́fẹ́ líle ati ìjì.” Da èrò wọn rú, OLUWA, kí o sì dà wọ́n lédè rú; nítorí ìwà ipá ati asọ̀ pọ̀ ninu ìlú. Tọ̀sán-tòru ni wọ́n ń yí orí odi rẹ̀ ká; ìwà ìkà ati ìyọnu ni ó sì pọ̀ ninu rẹ̀. Ìparun wà ninu rẹ̀; ìnilára ati ìwà èrú kò sì kúrò láàrin ìgboro rẹ̀. Bí ó bá ṣe pé ọ̀tá ní ń gàn mí, ǹ bá lè fara dà á. Bí ó bá ṣe pé ẹni tí ó kórìíra mi ní ń gbéraga sí mi, ǹ bá fara pamọ́ fún un. Ṣugbọn ìwọ ni; ìwọ tí o jẹ́ irọ̀ mi, alábàárìn mi, ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́. À ti jọ máa sọ ọ̀rọ̀ dídùndídùn pọ̀ rí; a sì ti jọ rìn ní ìrẹ́pọ̀ ninu ilé Ọlọrun. Jẹ́ kí ikú jí àwọn ọ̀tá mi pa; kí wọ́n lọ sinu isà òkú láàyè; kí wọ́n wọ ibojì lọ pẹlu ìpayà. Ṣugbọn èmi ké pe Ọlọrun; OLUWA yóo sì gbà mí. Mò ń ráhùn tọ̀sán-tòru, mo sì ń kérora; OLUWA óo gbọ́ ohùn mi. Yóo yọ mí láìfarapa, ninu ogun tí mò ń jà, nítorí ọ̀pọ̀ ni àwọn tí wọ́n dojú kọ mí, tí wọn ń bá mi jà. Ọlọrun tí ó gúnwà láti ìgbàanì yóo gbọ́, yóo sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, nítorí pé wọn kò pa ìwà wọn dà, wọn kò sì bẹ̀rù Ọlọrun. Alábàárìn mi gbógun ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó yẹ àdéhùn rẹ̀. Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ dùn ju oyin lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìjà ni ó wà lọ́kàn rẹ̀; ọ̀rọ̀ rẹ̀ tutù ju omi àmù lọ, ṣugbọn idà aṣekúpani ni. Kó gbogbo ìṣòro rẹ lé OLUWA lọ́wọ́, yóo sì gbé ọ ró; kò ní jẹ́ kí á ṣí olódodo ní ipò pada. Ṣugbọn ìwọ, Ọlọrun, o óo sọ àwọn apani ati àwọn alárèékérekè, sinu kòtò ìparun; wọn kò ní lo ìdajì ọjọ́ ayé wọn. Ṣugbọn èmi óo gbẹ́kẹ̀lé ọ. Ṣàánú mi, Ọlọrun, nítorí pé àwọn eniyan ń lépa mi; ọ̀tá gbógun tì mí tọ̀sán-tòru. Àwọn ọ̀tá ń lépa mi tọ̀sán-tòru, ọpọlọpọ ní ń bá mi jà tìgbéraga-tìgbéraga. Nígbà tí ẹ̀rù bá ń bà mí, èmi yóo gbẹ́kẹ̀lé ọ. Ọlọrun, mo yìn ọ́ fún ọ̀rọ̀ rẹ, ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé láìbẹ̀rù; kí ni eniyan ẹlẹ́ran ara lè fi mí ṣe? Tọ̀sán-tòru ni wọ́n ń da ọ̀rọ̀ mi rú; ibi ni gbogbo èrò tí wọn ń gbà sí mi. Wọ́n kó ara wọn jọ, wọ́n sápamọ́, wọ́n ń ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ mi, bí wọn ṣé ń dọdẹ ẹ̀mí mi. Nítorí náà, san ẹ̀san ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún wọn; ninu ibinu rẹ, Ọlọrun, ré àwọn eniyan yìí lulẹ̀. O sá mọ gbogbo ìdààmú mi; ati bí omijé mi ti pọ̀ tó, wọ́n ṣá wà ní àkọsílẹ̀ ninu ìwé rẹ. A óo lé àwọn ọ̀tá mi pada ní ọjọ́ tí mo bá ké pè ọ́. Mo mọ̀ dájú pé Ọlọrun ń bẹ fún mi. Ọlọrun, tí mo yin ọ̀rọ̀ rẹ̀, OLUWA, tí mo yin ọ̀rọ̀ rẹ̀; Ọlọrun ni mo gbẹ́kẹ̀lé láìbẹ̀rù. Kí ni eniyan ẹlẹ́ran ara lè fi mí ṣe? Èmi óo san ẹ̀jẹ́ mi fún ọ, Ọlọrun; n óo sì mú ẹbọ ọpẹ́ wá fún ọ. Nítorí pé o ti gba ẹ̀mí mi lọ́wọ́ ikú, o gbà mí, o kò jẹ́ kí n kọsẹ̀, kí n lè máa rìn níwájú Ọlọrun ninu ìmọ́lẹ̀ ìyè. Ṣàánú mi, Ọlọrun, ṣàánú mi, nítorí ìwọ ni ààbò mi; abẹ́ òjìji apá rẹ ni n óo fi ṣe ààbò mi, títí gbogbo àjálù wọnyi yóo fi kọjá. Mo ké pe Ọlọrun Ọ̀gá Ògo, Ọlọrun tí ó mú èrò rẹ̀ ṣẹ fún mi. Yóo ranṣẹ láti ọ̀run wá, yóo gbà mí là, yóo dójú ti àwọn tí ń lépa ẹ̀mí mi. Ọlọrun yóo fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ rẹ̀ hàn! Ààrin àwọn kinniun ni mo dùbúlẹ̀ sí, àwọn tí ń jẹ eniyan ní ìjẹ ìwọ̀ra; eyín wọn dàbí ọ̀kọ̀ ati ọfà, ahọ́n wọn sì dàbí idà. Gbé ara rẹ ga, Ọlọrun, gbé ara rẹ ga ju ọ̀run lọ, kí ògo rẹ sì tàn ká gbogbo ayé. Wọ́n dẹ àwọ̀n sí ojú ọ̀nà mi; ìpọ́njú dorí mi kodò. Wọ́n gbẹ́ kòtò sílẹ̀ dè mí, ṣugbọn àwọn fúnra wọn ni wọ́n jìn sí i. Ọkàn mi dúró ṣinṣin, Ọlọrun, ọkàn mi dúró ṣinṣin! N óo kọrin, n óo sì máa yìn ọ́. Jí, ìwọ ọkàn mi! Ẹ jí, ẹ̀yin ohun èlò orin, ati hapu, èmi alára náà yóo jí ní òwúrọ̀ kutukutu. OLUWA, n óo máa fi ọpẹ́ fún ọ láàrin àwọn eniyan; n óo sì máa kọrin ìyìn sí ọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè. Nítorí pé ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi, ó ga ju ọ̀run lọ, òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run. Gbé ara rẹ ga, Ọlọrun, gbé ara rẹ ga ju ọ̀run lọ, kí ògo rẹ sì tàn ká gbogbo ayé. Ǹjẹ́ ìpinnu tí ẹ̀ ń ṣe tọ̀nà, ẹ̀yin aláṣẹ? Ǹjẹ́ ẹ̀ ń ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan ní ọ̀nà ẹ̀tọ́? Rárá o! Ibi ni ẹ̀ ń fi ọkàn yín rò, iṣẹ́ burúkú ni ẹ sì ń fi ọwọ́ yín ṣe láyé. Láti inú oyún ni àwọn eniyan burúkú ti ṣìnà, láti ọjọ́ tí a ti bí wọn ni wọ́n tí ń ṣìṣe, tí wọn ń purọ́. Wọ́n ní oró bí oró ejò, wọ́n dití bíi paramọ́lẹ̀ tí ó di etí ara rẹ̀, kí ó má baà gbọ́ ohùn afunfèrè, tabi ìpè adáhunṣe. Kán eyín mọ́ wọn lẹ́nu, Ọlọrun; OLUWA! Yọ ọ̀gàn àwọn ẹgbọ̀rọ̀ kinniun. Jẹ́ kí wọ́n rá, kí wọn ṣàn lọ bí omi; kí á tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bíi koríko, kí wọn sì rọ. Kí wọn dàbí ìgbín tí a tẹ̀ ní àtẹ̀rẹ́, tí ó domi, ati bí òkúmọ tí kò fojú kan ìmọ́lẹ̀ ayé rí. Lójijì, a ó ké eniyan burúkú lulẹ̀; ìjì ibinu Ọlọrun yóo sì gbá wọn lọ. Olódodo yóo yọ̀ nígbà tí ẹ̀san bá ń ké, yóo fi ẹsẹ̀ wọ́ àgbàrá ẹ̀jẹ̀ àwọn eniyan burúkú. Àwọn eniyan yóo wí nígbà náà pé, “Nítòótọ́, èrè ń bẹ fún olódodo; nítòótọ́, Ọlọrun ń bẹ tí ń ṣe ìdájọ́ ayé.” Gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, Ọlọrun mi; dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn tí ó gbógun tì mí. Gbà mí lọ́wọ́ àwọn aṣebi, kí o sì yọ mí lọ́wọ́ àwọn apànìyàn. Wò ó bí wọ́n ṣe lúgọ dè mí! OLUWA, àwọn jàǹdùkú eniyan kó ara wọn jọ láti pa mí lára, láìṣẹ̀, láìrò. Láìjẹ́ pé mo ṣẹ̀, wọ́n ń sáré kiri, wọ́n múra dè mí. Paradà, wá ràn mí lọ́wọ́, kí o sì rí i fúnra rẹ. Ìwọ, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli, jí gìrì, kí o jẹ gbogbo orílẹ̀-èdè níyà; má da ẹnìkan kan sí ninu àwọn tí ń fi ìwà ọ̀dàlẹ̀ pète ibi. Ní alaalẹ́, wọn á pada wá, wọn á máa hu bí ajá, wọn a sì máa kiri ìlú. Ẹ gbọ́ ohun tí wọn ń sọ jáde lẹ́nu, ẹ wo ahọ́n wọn bí idà; wọ́n sì ń wí ninu ara wọn pé, “Ta ni yóo gbọ́ ohun tí à ń sọ?” Ṣugbọn ìwọ OLUWA ń fi wọ́n rẹ́rìn-ín, o sì ń fi gbogbo orílẹ̀-èdè ṣe yẹ̀yẹ́. Ọlọrun, agbára mi, ojú rẹ ni mò ń wò, nítorí ìwọ, Ọlọrun, ni odi mi. Ọlọrun mi óo wá sọ́dọ̀ mi ninu ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀; Ọlọrun óo fún mi ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá mi. Má pa wọ́n, kí àwọn eniyan mi má baà gbàgbé; fi ọwọ́ agbára rẹ mì wọ́n, ré wọn lulẹ̀, OLUWA, ààbò wa! Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n fi ẹnu wọn dá, àní, nítorí ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ẹnu wọn sọ, jẹ́ kí ìgbéraga wọn kó bá wọn. Nítorí èpè tí wọ́n ṣẹ́ ati irọ́ tí wọ́n pa, fi ibinu pa wọ́n run. Pa wọ́n run kí wọn má sí mọ́, kí àwọn eniyan lè mọ̀ pé Ọlọrun jọba lórí Jakọbu, ati títí dé òpin ayé. Ní alaalẹ́ wọn á pada wá wọn á máa hu bí ajá, wọn á sì máa kiri ìlú. Wọn á máa fẹsẹ̀ wọ́lẹ̀, wọn á máa wá oúnjẹ kiri, bí wọn ò bá sì yó wọn á máa kùn. Ṣugbọn èmi ó kọrin ìyìn agbára rẹ; n óo kọrin sókè lówùúrọ̀, nípa ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀. Nítorí ìwọ ni o ti jẹ́ odi mi ìwọ sì ni ààbò mi nígbà ìpọ́njú. Ọlọrun, agbára mi, n óo kọ orin ìyìn fún ọ, nítorí ìwọ, Ọlọrun, ni odi mi, Ọlọrun tí ó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn mí. Ọlọrun, o ti kọ̀ wá sílẹ̀, o ti wó odi wa; o ti bínú, dákun, mú wa bọ̀ sípò. O ti mú kí ilẹ̀ mì tìtì; o ti mú kí ó yanu; dí gbogbo ibi tí ilẹ̀ ti ya, nítorí pé ó ń mì. O ti jẹ́ kí àwọn eniyan rẹ ní ọpọlọpọ ìnira, o ti fún wa ní ọtí mu tóbẹ́ẹ̀ tí à ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n. O ti ta àsíá ogun fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ, kí wọ́n baà lè rí ààbò lọ́wọ́ ọfà ọ̀tá. Kí á lè gba àyànfẹ́ rẹ là, fi ọwọ́ agbára rẹ ṣẹgun fún wa, kí o sì dá wa lóhùn. Ọlọrun ti sọ̀rọ̀ ninu ilé mímọ́ rẹ̀, ó ní, “Tayọ̀tayọ̀ ni n óo fi pín Ṣekemu, n óo sì pín àfonífojì Sukotu. Tèmi ni Gileadi, tèmi sì ni Manase; Efuraimu ni àkẹtẹ̀ àṣíborí mi, Juda sì ni ọ̀pá àṣẹ mi. Moabu ni ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi; lórí Edomu ni n óo bọ́ bàtà mi lé; n óo sì hó ìhó ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí Filistia.” Ta ni yóo mú mi wọ inú ìlú olódi náà? Ta ni yóo mú mi lọ sí Edomu? Ọlọrun, o kò ha ti kọ̀ wá sílẹ̀? Ọlọrun, o ò bá àwọn ọmọ ogun wa jáde lọ sójú ogun mọ́. Ràn wá lọ́wọ́, bá wa gbógun ti àwọn ọ̀tá wa, nítorí pé asán ni ìrànlọ́wọ́ eniyan. Pẹlu àtìlẹ́yìn Ọlọrun a óo ṣe akin, nítorí òun ni yóo tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀. Gbọ́ igbe mi, Ọlọrun, fetí sí adura mi. Láti ọ̀nà jíjìn réré ni mo ti ké pè ọ́, nígbà tí àárẹ̀ mú mi. Tọ́ mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ, nítorí ìwọ ni ààbò mi, ìwọ ni ilé ìṣọ́ tí ó lágbára láti dáàbò bò mí lọ́wọ́ ọ̀tá. Jẹ́ kí n máa gbé inú àgọ́ rẹ títí lae, kí n lè máa wà láìléwu lábẹ́ ààbò ìyẹ́ rẹ. Nítorí ìwọ, Ọlọrun, ti gbọ́ ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́; o ti fún mi ní ogún tí o pèsè fún àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ. Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba ó gùn; kí ó pẹ́ láyé kánrinkése. Kí ó máa gúnwà níwájú Ọlọrun títí lae; máa fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́ rẹ ṣọ́ ọ. Bẹ́ẹ̀ ni n óo máa kọ orin ìyìn orúkọ rẹ títí lae, nígbà tí mo bá ń san ẹ̀jẹ́ mi lojoojumọ. Ọlọrun nìkan ni mo fi sùúrù gbẹ́kẹ̀lé; ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìgbàlà mi ti wá. Òun nìkan ni àpáta ati olùgbàlà mi, òun ni odi mi, a kì yóo tì mí kúrò. Yóo ti pẹ́ tó, tí gbogbo yín yóo dojú kọ ẹnìkan ṣoṣo, láti pa, ẹni tí kò lágbára ju ògiri tí ó ti fẹ́ wó lọ, tabi ọgbà tí ó fẹ́ ya? Wọ́n fẹ́ ré e bọ́ láti ipò ọlá rẹ̀. Inú wọn a máa dùn sí irọ́. Wọ́n ń fi ẹnu wọn súre, ṣugbọn ní ọkàn wọn, èpè ni wọ́n ń ṣẹ́. Ọlọrun nìkan ni mo fi sùúrù gbẹ́kẹ̀lé, nítorí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí mi ti wá. Òun nìkan ni àpáta ati olùgbàlà mi, òun ni odi mi, a kì yóo tì mí kúrò. Ọwọ́ Ọlọrun ni ìgbàlà ati ògo mi wà; òun ni àpáta agbára mi ati ààbò mi. Ẹ gbẹ́kẹ̀lé e nígbà gbogbo, ẹ̀yin eniyan; ẹ tú ẹ̀dùn ọkàn yín palẹ̀ níwájú rẹ̀; OLUWA ni ààbò wa. Afẹ́fẹ́ lásán ni àwọn mẹ̀kúnnù; ìtànjẹ patapata sì ni àwọn ọlọ́lá; bí a bá gbé wọn lé ìwọ̀n, wọn kò lè tẹ̀wọ̀n; àpapọ̀ wọn fúyẹ́ ju afẹ́fẹ́ lọ. Má gbẹ́kẹ̀lé ìlọ́ni-lọ́wọ́-gbà, má sì fi olè jíjà yangàn; bí ọrọ̀ bá ń pọ̀ sí i, má gbé ọkàn rẹ lé e. Ọlọrun ti sọ̀rọ̀ níbìkan, mo sì ti gbọ́ ọ bí ìgbà mélòó kan pé, Ọlọrun ló ni agbára; ati pé, tìrẹ, OLUWA ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀. Ò máa san ẹ̀san fún eniyan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ bá ti rí. Ọlọrun, ìwọ ni Ọlọrun mi, mò ń wá ọ, ọkàn rẹ ń fà mí; bí ilẹ̀ tí ó ti ṣá, tí ó sì gbẹ ṣe máa ń kóǹgbẹ omi. Mo ti ń wò ọ́ ninu ilé mímọ́ rẹ, mo ti rí agbára ati ògo rẹ. Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ dára ju ìyè lọ, n óo máa yìn ọ́. N óo máa yìn ọ́ títí ayé mi; n óo máa tẹ́wọ́ adura sí ọ. Ẹ̀mí mi yóo ní ànító ati àníṣẹ́kù; n óo sì fi ayọ̀ kọ orin ìyìn sí ọ. Nígbà tí mo bá ranti rẹ lórí ibùsùn mi, tí mo bá ń ṣe àṣàrò nípa rẹ ní gbogbo òru; nítorí ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi, lábẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ ni mò ń fi ayọ̀ kọrin. Ẹ̀mí mi rọ̀ mọ́ ọ; ọwọ́ ọ̀tun rẹ ni ó gbé mi ró. Ṣugbọn àwọn tí ń wá ọ̀nà láti gba ẹ̀mí mi yóo sọ̀kalẹ̀ lọ sinu isà òkú. A ó fi idà pa wọ́n lójú ogun, ẹranko ni yóo sì jẹ òkú wọn. Ṣugbọn ọba yóo máa yọ̀ ninu Ọlọrun; gbogbo àwọn tí ń fi orúkọ OLUWA búra yóo máa fògo fún un; ṣugbọn a ó pa àwọn òpùrọ́ lẹ́nu mọ́. Ọlọrun, gbọ́ ìráhùn mi; pa mí mọ́ lọ́wọ́ ìdẹ́rùbà ọ̀tá; dáàbò bò mí lọ́wọ́ ọ̀tẹ̀ àwọn eniyan burúkú; kó mi yọ lọ́wọ́ ète àwọn aṣebi. Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn bí idà, wọ́n ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ burúkú bí ẹni ta ọfà; wọ́n ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí aláìṣẹ̀ láti ibùba wọn, láìbẹ̀rù, wọ́n ń ta ọfà ọ̀rọ̀ sí i lójijì. Wọ́n wonkoko mọ́ ète burúkú wọn; wọ́n ń gbìmọ̀ àtidẹ okùn sílẹ̀ níkọ̀kọ̀, wọ́n ń rò lọ́kàn wọn pé, “Ta ni yóo rí wa? Ta ni yóo wá ẹ̀ṣẹ̀ wa rí? Ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí ni a ti fi pète.” Áà, inú ọmọ eniyan jìn! Ṣugbọn Ọlọrun yóo ta wọ́n lọ́fà; wọn óo fara gbọgbẹ́ lójijì. Yóo pa wọ́n run nítorí ohun tí wọ́n fi ẹnu wọn sọ; gbogbo ẹni tí ó bá rí wọn ni yóo máa mirí nítorí wọn. Ẹ̀rù yóo sì ba gbogbo eniyan; wọn yóo máa sọ ohun tí Ọlọrun ti gbé ṣe, wọn yóo sì máa ronú nípa iṣẹ́ rẹ̀. Kí àwọn olódodo máa yọ̀ ninu OLUWA, kí wọ́n sì máa wá ààbò lọ́dọ̀ rẹ̀! Kí gbogbo ẹni pípé máa ṣògo. Ọlọrun, ìwọ ni ìyìn yẹ ní Sioni, ìwọ ni a óo san ẹ̀jẹ́ wa fún, ìwọ tí ń gbọ́ adura! Ọ̀dọ̀ rẹ ni gbogbo eniyan ń bọ̀, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ wa bá borí wa, ìwọ a máa dáríjì wá. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí o yàn, tí o mú wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, láti máa gbé inú àgbàlá rẹ. Àwọn ire inú ilé rẹ yóo tẹ́ wa lọ́rùn, àní, àwọn ire inú tẹmpili mímọ́ rẹ! Iṣẹ́ òdodo tí ó bani lẹ́rù ni o fi dá wa lóhùn, Ọlọrun olùgbàlà wa. Ìwọ ni gbogbo àwọn tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé gbẹ́kẹ̀lé, ati àwọn tí wọn wà lórí omi òkun ní ọ̀nà jíjìn réré. Ìwọ tí o fi agbára fi ìdí àwọn òkè ńlá múlẹ̀; tí o sì fi agbára di ara rẹ ní àmùrè. O mú híhó òkun dákẹ́ jẹ́ẹ́, ariwo ìgbì wọn rọlẹ̀ wọ̀ọ̀; o sì paná ọ̀tẹ̀ àwọn eniyan. Àwọn tí ń gbé ìpẹ̀kun ayé sì ń bẹ̀rù nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ; o mú kí àwọn eniyan, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀, hó ìhó ayọ̀. Ò ń ṣìkẹ́ ayé, o sì ń bomi rin ín, o mú kí ilẹ̀ jí kí ó sì lẹ́tù lójú; o mú kí omi kún inú odò ìwọ Ọlọrun, o mú kí ọkà hù lórí ilẹ̀; nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni o ṣe ṣètò rẹ̀. O bomi rin poro oko rẹ̀ lọpọlọpọ, o ṣètò àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀; o rọ òjò tó mú kí ilẹ̀ rọ̀, o sì mú kí ohun ọ̀gbìn rẹ̀ dàgbà. O mú kí ìkórè oko pọ̀ yanturu ní òpin ọdún; gbogbo ipa ọ̀nà rẹ sì kún fún ọpọlọpọ ìkórè oko. Gbogbo pápá oko kún fún ẹran ọ̀sìn, àwọn ẹ̀gbẹ́ òkè sì kún fún ohun ayọ̀, ẹran ọ̀sìn bo pápá oko bí aṣọ, ọkà bo gbogbo àfonífojì, ó sì so jìngbìnnì, wọ́n ń hó, wọ́n sì ń kọrin ayọ̀. Gbogbo ayé, ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọrun. Ẹ kọ orin ògo yin orúkọ rẹ̀; ẹ yìn ín, ẹ fògo fún un! Ẹ sọ fún Ọlọrun pé, “Iṣẹ́ rẹ bani lẹ́rù pupọ, agbára rẹ pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí àwọn ọ̀tá rẹ fi ń fi ìbẹ̀rù tẹríba fún ọ. Gbogbo ayé ní ń sìn ọ́; wọ́n ń kọ orin ìyìn fún ọ, wọ́n ń kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ.” Ẹ wá wo ohun tí Ọlọrun ṣe, iṣẹ́ tí ó ń ṣe láàrin ọmọ eniyan bani lẹ́rù. Ó sọ òkun di ìyàngbẹ ilẹ̀, àwọn eniyan fi ẹsẹ̀ rìn kọjá láàrin odò. Inú wa dùn níbẹ̀ nítorí ohun tí ó ṣe. Nípa agbára rẹ̀ ó ń jọba títí lae. Ó ń ṣọ́ àwọn orílẹ̀-èdè lójú mejeeji, kí àwọn ọlọ̀tẹ̀ má gbéraga sí i. Ẹ yin Ọlọrun wa, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, ẹ jẹ́ kí á gbọ́ ìró ìyìn rẹ̀; ẹni tí ó dá wa sí tí a fi wà láàyè, tí kò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa yẹ̀. Nítorí ìwọ, Ọlọrun, ti dán wa wò; o ti dán wa wò bíi fadaka tí a dà ninu iná. O jẹ́ kí á bọ́ sinu àwọ̀n; o sì di ẹrù wúwo lé wa lórí. O jẹ́ kí àwọn eniyan máa gùn wá lórí mọ́lẹ̀, a ti la iná ati omi kọjá; sibẹsibẹ o mú wa wá sí ibi tí ilẹ̀ ti tẹ́jú. N óo wá sinu ilé rẹ pẹlu ọrẹ ẹbọ sísun; n óo sì san ẹ̀jẹ́ mi fún ọ. Ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́, tí mo sì fi ẹnu mi sọ nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú. N óo fi ẹran àbọ́pa rú ẹbọ sísun sí ọ, èéfín ẹbọ àgbò yóo rú sókè ọ̀run, n óo fi akọ mààlúù ati òbúkọ rúbọ. Ẹ wá gbọ́, gbogbo ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Ọlọrun, n óo sì ròyìn ohun tí ó ṣe fún mi. Mo ké pè é, mo sì kọrin yìn ín. Bí mo bá gba ẹ̀ṣẹ̀ láyè ní ọkàn mi, OLUWA ìbá tí gbọ́ tèmi. Ṣugbọn nítòótọ́, Ọlọrun ti gbọ́; ó sì ti dáhùn adura mi. Ìyìn ni fún Ọlọrun, nítorí pé kò kọ adura mi; kò sì mú kí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ kúrò lórí mi. Kí Ọlọrun óo ṣàánú wa, kí ó bukun wa; kí ojú rẹ̀ tan ìmọ́lẹ̀ sí wa lára; kí gbogbo ayé lè mọ ọ̀nà rẹ̀; kí gbogbo orílẹ̀-èdè sì mọ ìgbàlà rẹ̀. Jẹ́ kí àwọn eniyan ó máa yìn ọ́, Ọlọrun; jẹ́ kí gbogbo eniyan máa yìn ọ́! Kí inú àwọn orílẹ̀-èdè ó dùn, kí wọn ó máa kọrin ayọ̀, nítorí pé ò ń ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan láìṣe ojuṣaaju; o sì ń tọ́ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ayé. Jẹ́ kí àwọn eniyan ó máa yìn ọ́, Ọlọrun; jẹ́ kí gbogbo eniyan máa yìn ọ́! Ilẹ̀ mú ọ̀pọ̀ ìkórè jáde; Ọlọrun, àní Ọlọrun wa, bukun wa. Ọlọrun bukun wa, kí gbogbo ayé máa bẹ̀rù rẹ̀. Kí Ọlọrun dìde, kí àwọn ọ̀tá rẹ tú ká. Kí àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ sá níwájú rẹ̀. Bí èéfín tií pòórá, bẹ́ẹ̀ ni kí wọn parẹ́; bí ìda tií yọ́ níwájú iná, bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn eniyan burúkú parun níwájú Ọlọrun. Ṣugbọn kí inú àwọn olódodo máa dùn, kí wọn máa yọ̀ níwájú Ọlọrun; kí wọn máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀. Ẹ kọrin sí Ọlọrun, ẹ kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ̀, ẹ pòkìkí ẹni tí ń gun ìkùukùu lẹ́ṣin. OLUWA ni orúkọ rẹ̀; ẹ máa yọ̀ níwájú rẹ̀. Baba àwọn aláìníbaba ati olùgbèjà àwọn opó ni Ọlọrun, ní ibùgbé rẹ̀ mímọ́. Ọlọrun, olùpèsè ibùjókòó fún àlejò tí ó nìkan wà; ẹni tí ó kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n jáde sinu ìdẹ̀ra, ṣugbọn ó sì fi àwọn ọlọ̀tẹ̀ sílẹ̀ ninu ilẹ̀ gbígbẹ. Ọlọrun, nígbà tí ò ń jáde lọ níwájú àwọn eniyan rẹ, nígbà tí ò ń yan la aṣálẹ̀ já, ilẹ̀ mì tìtì, ọ̀run pàápàá rọ òjò, níwájú Ọlọrun, Ọlọrun Sinai, àní, níwájú Ọlọrun Israẹli. Ọlọrun, ọpọlọpọ ni òjò tí o rọ̀ sílẹ̀; o sì mú ilẹ̀ ìní rẹ tí ó ti gbẹ pada bọ̀ sípò. Àwọn eniyan rẹ rí ibùgbé lórí rẹ̀; Ọlọrun, ninu oore ọwọ́ rẹ, o pèsè fún àwọn aláìní. OLUWA fọhùn, ogunlọ́gọ̀ sì ni àwọn tí ó kéde ọ̀rọ̀ rẹ̀. Gbogbo àwọn ọba ni ó sá tàwọn tọmọ ogun wọn; àwọn obinrin tí ó wà nílé, ati àwọn tí ó wà ní ibùjẹ ẹran rí ìkógun pín: fadaka ni wọ́n yọ́ bo apá ère àdàbà; wúrà dídán sì ni wọ́n yọ́ bo ìyẹ́ rẹ̀. Nígbà tí Olodumare tú àwọn ọba ká, ní òkè Salimoni, yìnyín bọ́. Áà! Òkè Baṣani, òkè ńlá; Áà! Òkè Baṣani, òkè olórí pupọ. Ẹ̀yin òkè olórí pupọ, kí ló dé tí ẹ̀ ń fi ìlara wo òkè tí Ọlọrun fẹ́ràn láti máa gbé, ibi tí OLUWA yóo máa gbé títí lae? OLUWA sọ̀kalẹ̀ láti òkè Sinai sí ibi mímọ́ rẹ̀ pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun lọ́nà ẹgbẹrun kẹ̀kẹ́ ogun, ẹgbẹẹgbẹrun lọ́nà ẹgbẹrun. Ó gun òkè gíga, ó kó àwọn eniyan nígbèkùn; ó gba ẹ̀bùn lọ́wọ́ àwọn eniyan, ati lọ́wọ́ àwọn ọlọ̀tẹ̀ pàápàá. OLUWA Ọlọrun yóo máa gbébẹ̀. Ìyìn ni fún OLUWA, Ọlọrun ìgbàlà wa, tí ń bá wa gbé ẹrù wa lojoojumọ. Ọlọrun tí ń gbani là ni Ọlọrun wa; OLUWA Ọlọrun ni ń yọni lọ́wọ́ ikú. Dájúdájú, OLUWA yóo fọ́ orí àwọn ọ̀tá rẹ̀; yóo fọ́ àtàrí àwọn tí ń dẹ́ṣẹ̀. OLUWA ní, “N óo kó wọn pada láti Baṣani, n óo kó wọn pada láti inú ibú omi òkun, kí ẹ lè fi ẹsẹ̀ wọ́ àgbàrá ẹ̀jẹ̀ àwọn ọ̀tá yín, kí àwọn ajá yín lè lá ẹ̀jẹ̀ wọn bí ó ti wù wọ́n.” A ti rí ọ, Ọlọrun, bí o tí ń yan lọ, pẹlu ọ̀wọ́ èrò tí ń tẹ̀lé ọ lẹ́yìn. Ẹ wo Ọlọrun mi, ọba mi, bí ó ti ń yan wọ ibi mímọ́ rẹ̀, àwọn akọrin níwájú, àwọn onílù lẹ́yìn, àwọn ọmọbinrin tí ń lu samba láàrin. “Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọrun ninu àwùjọ eniyan, ẹ̀yin ìran Israẹli, ẹ fi ọpẹ́ fún OLUWA.” Ẹ wo Bẹnjamini tí ó kéré jù níwájú, ẹ wo ogunlọ́gọ̀ àwọn ìjòyè Juda, ẹ wo àwọn ìjòyè Sebuluni ati ti Nafutali. Fi agbára rẹ hàn, Ọlọrun, fi agbára tí o ti fi jà fún wa hàn. Nítorí Tẹmpili rẹ tí ó wà ní Jerusalẹmu, àwọn ọba yóo gbé ẹ̀bùn wá fún ọ. Bá àwọn ẹranko ẹ̀dá tí ń gbé inú èèsún ní Ijipti wí; àwọn akọ mààlúù, láàrin agbo ẹran àwọn orílẹ̀-èdè. Tẹ àwọn tí ó fẹ́ràn owó mọ́lẹ̀; fọ́n àwọn orílẹ̀-èdè tí ó fẹ́ràn ogun ká. Jẹ́ kí àwọn ikọ̀ wá láti Ijipti, kí àwọn ará Kuṣi tẹ́wọ́ adura sí Ọlọrun. Ẹ kọ orin sí Ọlọrun ẹ̀yin ìjọba ayé; ẹ kọ orin ìyìn sí OLUWA. Ẹni tí ń gun awọsanma lẹ́ṣin, àní awọsanma àtayébáyé; ẹ gbọ́ bí ó ṣe ń sán ààrá, ẹ gbọ́ ohùn alágbára. Ẹ bu ọlá fún Ọlọrun, ẹni tí ògo rẹ̀ wà lórí Israẹli; tí agbára rẹ̀ sì hàn lójú ọ̀run. Ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ni Ọlọrun ní ibi mímọ́ rẹ̀, Ọlọrun Israẹli; òun ni ó ń fún àwọn eniyan rẹ̀ ní ọlá ati agbára. Ìyìn ni fún Ọlọrun! Gbà mí, Ọlọrun, nítorí omi ti mù mí dé ọrùn. Mo ti rì sinu irà jíjìn, níbi tí kò ti sí ohun ìfẹsẹ̀tẹ̀; mo ti bọ́ sinu ibú, omi sì ti bò mí mọ́lẹ̀. Mo sọkún títí àárẹ̀ mú mi, ọ̀nà ọ̀fun mi gbẹ, ojú mi sì di bàìbàì, níbi tí mo ti dúró, tí mò ń wo ojú ìwọ Ọlọrun mi. Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìí pọ̀, wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ. Àwọn tí ó fẹ́ pa mí run lágbára. Àwọn ọ̀tá mi ń parọ́ mọ́ mi, àwọn nǹkan tí n kò jí ni wọ́n ní kí n fi dandan dá pada. Ọlọrun, o mọ ìwà òmùgọ̀ mi, àwọn àṣìṣe mi kò sì fara pamọ́ fún ọ. Má tìtorí tèmi dójúti àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, má sì tìtorí mi sọ àwọn tí ń wá ọ di ẹni àbùkù, Ọlọrun Israẹli. Nítorí tìrẹ ni mo ṣe di ẹni ẹ̀gàn, tí ìtìjú sì bò mí. Mo ti di àlejò lọ́dọ̀ àwọn arakunrin mi, mo sì di àjèjì lọ́dọ̀ àwọn ọmọ ìyá mi. Nítorí pé ìtara ilé rẹ ni ó jẹ mí lógún, ìwọ̀sí àwọn tí ó ń pẹ̀gàn rẹ sì bò mí mọ́lẹ̀. Nígbà tí mo fi omijé gbààwẹ̀, ó di ẹ̀gàn fún mi. Nígbà tí mò ń wọ aṣọ ọ̀fọ̀, mo di ẹni àmúpòwe. Èmi ni àwọn tí ń jókòó lẹ́nu ibodè fi ń ṣe ọ̀rọ̀ sọ; àwọn ọ̀mùtí sì ń fi mí ṣe orin kọ. Ṣugbọn ní tèmi, OLUWA, ìwọ ni mò ń gbadura sí ní àkókò tí ó bá yẹ, Ọlọrun, ninu ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, ninu agbára ìgbàlà rẹ, Ọlọrun dá mi lóhùn. Yọ mí ninu irà yìí, má jẹ́ kí n rì, gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi. Má jẹ́ kí ìgbì omi bò mí mọ́lẹ̀, kí ibú omi má gbé mi mì, kí isà òkú má sì padé mọ́ mi. Dá mi lóhùn, OLUWA, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ dára; fojú rere wò mí, gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ àánú rẹ. Má ṣe fi ojú pamọ́ fún èmi, iranṣẹ rẹ, nítorí tí mo wà ninu ìdààmú, yára dá mi lóhùn. Sún mọ́ mi, rà mí pada, kí o sì tú mi sílẹ̀ nítorí àwọn ọ̀tá mi! O mọ ẹ̀gàn mi, o mọ ìtìjú ati àbùkù mi; o sì mọ gbogbo àwọn ọ̀tá mi. Ẹ̀gàn ti mú kí inú mi bàjẹ́, tóbẹ́ẹ̀ tí ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì mò ń retí àánú ṣugbọn kò sí; mò ń retí olùtùnú, ṣugbọn n kò rí ẹnìkan. Iwọ ni wọ́n sọ di oúnjẹ fún mi, nígbà tí òùngbẹ sì ń gbẹ mí, ọtí kíkan ni wọ́n fún mi mu. Jẹ́ kí tabili oúnjẹ tí wọ́n tẹ́ fún ara wọn di ẹ̀bìtì fún wọn; kí àsè ẹbọ wọn sì di tàkúté. Jẹ́ kí ojú wọn ṣú, kí wọn má lè ríran; kí gbogbo ara wọn sì máa gbọ̀n rìrì. Rọ òjò ibinu rẹ lé wọn lórí, kí o sì jẹ́ kí wọ́n rí gbígbóná ibinu rẹ. Kí ibùdó wọn ó di ahoro, kí ẹnikẹ́ni má sì gbé inú àgọ́ wọn. Nítorí ẹni tí o ti kọlù ni wọ́n tún gbógun tì; ẹni tí o ti ṣá lọ́gbẹ́ ni wọ́n sì tún ń pọ́n lójú. Fi ẹ̀sùn kún ẹ̀sùn wọn; má sì jẹ́ kí wọ́n rí ìdáláre lọ́dọ̀ rẹ. Pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò ninu ìwé ìyè; kí á má sì kọ orúkọ wọn mọ́ ti àwọn olódodo. Ojú ń pọ́n mi, mo sì ń jẹ̀rora; Ọlọrun, jẹ́ kí ìgbàlà rẹ gbé mi lékè! Èmi ó fi orin yin orúkọ Ọlọrun; n óo fi ọpẹ́ gbé e ga. Èyí yóo tẹ́ Ọlọrun lọ́rùn ju akọ mààlúù lọ, àní, akọ mààlúù tòun tìwo ati pátákò rẹ̀. Àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóo rí i, inú wọn yóo dùn; ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wá Ọlọrun, ẹ jẹ́ kí ọkàn yín sọjí. Nítorí OLUWA a máa gbọ́ ti àwọn aláìní, kì í sìí kẹ́gàn àwọn eniyan rẹ̀ tí ó wà ní ìgbèkùn. Jẹ́ kí ọ̀run ati ayé kí ó yìn ín, òkun ati gbogbo ohun tí ó ń rìn káàkiri ninu wọn. Nítorí Ọlọrun yóo gba Sioni là; yóo sì tún àwọn ìlú Juda kọ́; àwọn iranṣẹ rẹ̀ yóo máa gbé inú rẹ̀, yóo sì di tiwọn. Àwọn ọmọ àwọn iranṣẹ rẹ̀ yóo jogún rẹ̀; àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ̀ yóo sì máa gbé inú rẹ̀. Ọlọrun, dákun, gbà mí, yára, OLUWA, ràn mí lọ́wọ́. Jẹ́ kí ojú ti gbogbo àwọn tí wọn fẹ́ gba ẹ̀mí mi kí ìdàrúdàpọ̀ bá wọn; jẹ́ kí á lé àwọn tí ń wá ìpalára mi pada sẹ́yìn, kí wọn sì tẹ́. Jẹ́ kí jìnnìjìnnì bo àwọn tí ń yọ̀ mí, tí ń ṣe jàgínní mi; kí wọn sì gba èrè ìtìjú. Kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ máa yọ̀ nítorí rẹ, kí inú wọn sì máa dùn, kí àwọn tí ó fẹ́ràn ìgbàlà rẹ máa wí nígbà gbogbo pé, “Ọlọrun tóbi!” Ṣugbọn ní tèmi, olùpọ́njú ati aláìní ni mí, yára wá sọ́dọ̀ mi, Ọlọrun! Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi ati olùgbàlà mi, má pẹ́ OLÚWA. OLUWA, ìwọ ni mo sá di; má jẹ́ kí ojú ó tì mí laelae! Gbà mí, kí o sì yọ mí nítorí òdodo rẹ; tẹ́tí sí mi kí o sì gbà mí là! Máa ṣe àpáta ààbò fún mi, jẹ́ odi alágbára fún mi kí o sì gbà mí, nítorí ìwọ ni ààbò ati odi mi. Ọlọrun mi, gbà mí lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú, àwọn alaiṣootọ ati ìkà. Nítorí ìwọ OLUWA, ni ìrètí mi, OLUWA, Ọlọrun mi, ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé láti ìgbà èwe mi. Ìwọ ni mo gbára lé láti inú oyún; ìwọ ni o mú mi jáde láti inú ìyá mi. Ìwọ ni n óo máa yìn nígbà gbogbo. Mo di ẹni àmúpòwe fún ọpọlọpọ eniyan, ṣugbọn ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára. Ẹnu mi kún fún ìyìn rẹ, ó kún fún ògo rẹ tọ̀sán-tòru. Má ta mí nù ní ìgbà ogbó mi; má sì gbàgbé mi nígbà tí n kò bá lágbára mọ́. Nítorí pé àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi, àwọn tí ń lépa ẹ̀mí mi ti pàmọ̀ pọ̀, wọ́n ní, “Ọlọrun ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀; ẹ lé e, ẹ mú un; nítorí kò sí ẹni tí yóo gbà á sílẹ̀ mọ́.” Ọlọrun, má jìnnà sí mi; yára, Ọlọrun mi, ràn mí lọ́wọ́! Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn alátakò mi, kí wọn parun; kí ẹ̀gàn ati ìtìjú bo àwọn tí ń wá ìpalára mi. Ní tèmi, èmi ó máa ní ìrètí nígbà gbogbo, n óo sì túbọ̀ máa yìn ọ́. N óo máa ṣírò iṣẹ́ rere rẹ, n óo máa ròyìn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ tọ̀sán-tòru, nítorí wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí n kò lè mọ iye wọn. N óo wá ninu agbára OLUWA Ọlọrun, n óo máa kéde iṣẹ́ òdodo rẹ, àní, iṣẹ́ òdodo tìrẹ nìkan. Ọlọrun, láti ìgbà èwe mi ni o ti kọ́ mi, títí di òní ni mo sì ń polongo iṣẹ́ ìyanu rẹ, Nisinsinyii tí mo ti dàgbà, tí ewú sì ti gba orí mi, Ọlọrun, má kọ̀ mí sílẹ̀, títí tí n óo fi ròyìn iṣẹ́ ńlá rẹ, àní, iṣẹ́ agbára rẹ, fún gbogbo àwọn ìran tí ń bọ̀. Ọlọrun, iṣẹ́ òdodo rẹ kan ojú ọ̀run, ìwọ tí o ṣe nǹkan ńlá, Ọlọrun, ta ni ó dàbí rẹ? O ti jẹ́ kí n rí ọpọlọpọ ìpọ́njú ńlá, ṣugbọn óo tún mú ìgbé ayé mi pada bọ̀ sípò; óo tún ti gbé mi dìde láti inú isà òkú. O óo fi kún ọlá mi, o óo sì tún tù mí ninu. Èmi náà óo máa fi hapu yìn ọ́, nítorí òtítọ́ rẹ, Ọlọrun mi; n óo máa fi ohun èlò orin yìn ọ́, ìwọ ẹni mímọ́ Israẹli. N óo máa kígbe fún ayọ̀, nígbà tí mo bá ń kọ orin ìyìn sí ọ; ẹ̀mí mi tí o ti kó yọ, yóo ké igbe ayọ̀. Ẹnu mi yóo ròyìn iṣẹ́ rẹ tọ̀sán-tòru, nítorí a ti ṣẹgun àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára, a sì ti dójú tì wọ́n. Ọlọrun, gbé ìlànà òtítọ́ rẹ lé ọba lọ́wọ́; kọ́ ọmọ ọba ní ọ̀nà òdodo rẹ. Kí ó lè máa fi òdodo ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan rẹ, kí ó sì máa dá ẹjọ́ àwọn tí ìyà ń jẹ ní ọ̀nà ẹ̀tọ́; kí àwọn eniyan tí ó gbé orí òkè ńlá lè rí alaafia, kí nǹkan sì dára fún àwọn tí ń gbé orí òkè kéékèèké. Jẹ́ kí ó máa gbèjà àwọn eniyan tí ìyà ń jẹ; kí ó máa gba àwọn ọmọ talaka sílẹ̀; kí ó sì rún àwọn aninilára wómúwómú. Ọlọrun, jẹ́ kí àwọn eniyan rẹ máa bẹ̀rù rẹ láti ìran dé ìran, níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ń ràn, tí òṣùpá sì ń yọ. Jẹ́ kí ọba ó dàbí òjò tí ó rọ̀ sórí koríko tí a ti gé àní, bí ọ̀wààrà òjò tí ń rin ilẹ̀. Kí ìwà rere ó gbèrú ní ìgbà tirẹ̀; kí alaafia ó gbilẹ̀ títí tí òṣùpá kò fi ní yọ mọ́. Kí ìjọba rẹ̀ ó lọ láti òkun dé òkun, ati láti odò ńlá títí dé òpin ayé. Àwọn tí ń gbé aṣálẹ̀ yóo máa foríbalẹ̀ fún un; àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóo sì máa fi ẹnu gbo ilẹ̀ níwájú rẹ̀. Àwọn ọba Taṣiṣi ati àwọn ọba erékùṣù gbogbo yóo máa san ìṣákọ́lẹ̀ fún un; àwọn ọba Ṣeba ati ti Seba yóo máa mú ẹ̀bùn wá. Gbogbo àwọn ọba yóo máa wólẹ̀ fún un; gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì máa sìn ín. Nítorí pé a máa gba talaka tí ó bá ké pè é sílẹ̀; a sì máa gba àwọn tí ìyà ń jẹ sílẹ̀, ati àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́. A máa ṣíjú àánú wo àwọn aláìní ati talaka, a sì máa gba àwọn talaka sílẹ̀. A máa gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn aninilára ati oníwà ipá, ẹ̀mí wọn sì ṣe iyebíye ní ojú rẹ̀. Ẹ̀mí rẹ̀ yóo gùn, a óo máa fi wúrà Ṣeba ta á lọ́rẹ, a óo máa gbadura fún un nígbà gbogbo; a óo sì máa súre fún un tọ̀sán-tòru. Ọkà yóo pọ̀ lóko, yóo máa mì lẹ̀gbẹ̀ lórí òkè; èso rẹ̀ yóo dàbí ti Lẹbanoni, eniyan yóo pọ̀ ní ìlú, bíi koríko ninu pápá. Orúkọ ọba óo wà títí lae, òkìkí rẹ̀ óo sì máa kàn níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ń ràn; àwọn eniyan óo máa fi orúkọ rẹ̀ súre fún ara wọn, gbogbo orílẹ̀-èdè óo sì máa pè é ní olóríire. Ẹni-ìyìn ni OLUWA Ọlọrun Israẹli, ẹni tí ó ń ṣe iṣẹ́ ìyanu tí ẹlòmíràn kò lè ṣe. Ẹni ìyìn títí lae ni ẹni tí orúkọ rẹ̀ lókìkí, kí òkìkí rẹ̀ gba ayé kan! Amin! Amin. Níbi tí adura Dafidi ọmọ Jese parí sí nìyí. Nítòótọ́ Ọlọrun ṣeun fún Israẹli, ó ṣeun fún àwọn tí ọkàn wọn mọ́. Ṣugbọn, ní tèmi, mo fẹ́rẹ̀ yọ̀ ṣubú, ẹsẹ̀ mi fẹ́rẹ̀ tàsé. Nítorí mò ń ṣe ìlara àwọn onigbeeraga nígbà tí mo rí ọrọ̀ àwọn eniyan burúkú. Wọn kì í jẹ ìrora kankan, ara wọn dá pé, ó sì jọ̀lọ̀. Wọn kì í ní wahala bí àwọn ẹlòmíràn; ìyọnu tíí dé bá àwọn ẹlòmíràn kì í dé ọ̀dọ̀ wọn. Nítorí náà, wọn á kó ìgbéraga bọ ọrùn bí ẹ̀gbà, wọn á fi ìwà ipá bora bí aṣọ. Wọ́n sanra tóbẹ́ẹ̀ tí ojú wọn yíbò; èrò òmùgọ̀ sì kún ọkàn wọn ní àkúnwọ́sílẹ̀. Wọ́n ń pẹ̀gàn eniyan, wọ́n ń sọ̀rọ̀ pẹlu ìlara; wọ́n sì ń fi ìgbéraga halẹ̀. Wọ́n ń fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọrun; wọn a sì máa sọ̀rọ̀ ìgbéraga káàkiri ayé. Nítorí náà, àwọn eniyan á yipada, wọn á fara mọ́ wọn, wọn á máa yìn wọ́n, láìbìkítà fún ibi tí wọn ń ṣe. Wọn á máa wí pé, “Báwo ni Ọlọrun ṣe lè mọ̀? Ǹjẹ́ Ọ̀gá Ògo tilẹ̀ ní ìmọ̀?” Ẹ wò ó! Ayé àwọn eniyan burúkú nìwọ̀nyí; ara dẹ̀ wọ́n nígbà gbogbo, ọrọ̀ wọn sì ń pọ̀ sí i. Lásán ni gbogbo aáyan mi láti rí i pé ọkàn mi mọ́, tí mo sì yọwọ́-yọsẹ̀ ninu ibi. Nítorí pé tọ̀sán-tòru ni mò ń rí ìyọnu; láràárọ̀ ni à ń jẹ mí níyà. Bí mo bá ní, “N óo sọ̀rọ̀ báyìí,” n óo kó àwọn ọmọ rẹ ṣìnà. Ṣugbọn nígbà tí mo rò bí nǹkan wọnyi ṣe lè yé mi, mo rí i pé iṣẹ́ tíí dáni lágara ni. Àfi ìgbà tí mo wọ ibi mímọ́ Ọlọrun lọ, ni mo tó wá rí òye ìgbẹ̀yìn wọn. Nítòótọ́ ibi tí ń yọ̀ ni ó gbé wọn lé, ó sì mú kí wọn ṣubú sinu ìparun. Wò ó bí wọn ṣe parun lọ́gán, tí ìpayà sì gbá wọn lọ patapata. Wọ́n dàbí àlá tíí pòórá nígbà tí eniyan bá ta jí. OLUWA, nígbà tí o bá jí gìrì, wọn óo pòórá. Nígbà tí ọkàn mí bàjẹ́, tí ọ̀rọ̀ náà gbóná lára mi, mo hùwà òmùgọ̀, n kò sì lóye, mo sì dàbí ẹranko lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ. Sibẹsibẹ nígbà gbogbo ni mo wà lọ́dọ̀ rẹ; o sì di ọwọ́ ọ̀tún mi mú. Ò ń fi ìmọ̀ràn rẹ tọ́ mi sọ́nà; lẹ́yìn náà, o óo sì gbà mí sinu ògo. Ta ni mo ní lọ́run lẹ́yìn rẹ? Kò sì sí ohun kan tí ó wù mí láyé yìí bíkòṣe ìwọ. Àárẹ̀ lè mú ara ati ẹ̀mí mi, ṣugbọn Ọlọrun ni agbára ẹ̀mí mi, ati ìpín mi títí lae. Ó dájú pé àwọn tí ó jìnnà sí ọ yóo ṣègbé, o óo sì pa àwọn tí ó bá ṣe alaiṣootọ sí ọ run. Ní tèmi o, ó dára láti súnmọ́ Ọlọrun; mo ti fi ìwọ OLUWA Ọlọrun ṣe ààbò mi, kí n lè máa ròyìn gbogbo iṣẹ́ rẹ. Ọlọrun, kí ló dé tí o fi ta wá nù títí ayé? Kí ló dé tí inú rẹ fi ń ru sí àwa aguntan pápá rẹ? Ranti ìjọ eniyan rẹ tí o ti rà ní ìgbà àtijọ́, àwọn ẹ̀yà tí o rà pada láti fi ṣe ogún tìrẹ; ranti òkè Sioni níbi tí o ti ń gbé rí. Rìn káàkiri kí o wo bí gbogbo ilẹ̀ ti di ahoro, wo bí ọ̀tá ti ba gbogbo nǹkan jẹ́ ninu ibi mímọ́ rẹ. Àwọn ọ̀tá rẹ bú ramúramù ninu ilé ìsìn rẹ; wọ́n ta àsíá wọn gẹ́gẹ́ bí àmì ìṣẹ́gun. Wọ́n dàbí ẹni tí ó gbé àáké sókè, tí ó fi gé igi ìṣẹ́pẹ́. Gbogbo pákó tí a fi dárà sí ara ògiri ni wọ́n fi àáké ati òòlù fọ́. Wọ́n jó ibi mímọ́ rẹ kanlẹ̀; wọ́n sì ba ilé tí a ti ń pe orúkọ rẹ jẹ́. Wọ́n pinnu lọ́kàn wọn pé, “A óo bá wọn kanlẹ̀ patapata.” Wọ́n dáná sun gbogbo ilé ìsìn Ọlọrun tí ó wà ní ilẹ̀ náà. A kò rí àsíá wa mọ́, kò sí wolii mọ́; kò sì sí ẹnìkan ninu wa tí ó mọ bí ìṣòro wa yóo ti pẹ́ tó. Yóo ti pẹ́ tó, Ọlọrun, tí ọ̀tá yóo máa fi ọ́ ṣẹ̀fẹ̀? Ṣé títí ayé ni ọ̀tá yóo máa gan orúkọ rẹ ni? Kí ló dé tí o ò ṣe nǹkankan? Kí ló dé tí o káwọ́ gbera? Ọlọrun, ìwọ ṣá ni ọba wa láti ìbẹ̀rẹ̀ wá; ìwọ ni o máa ń gbà wá là láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè. Ìwọ ni o fi agbára rẹ pín òkun níyà; o fọ́ orí àwọn ẹranko ńlá inú omi. Ìwọ ni o fọ́ orí Lefiatani túútúú; o sì fi òkú rẹ̀ ṣe ìjẹ fún àwọn ẹranko inú aṣálẹ̀. Ìwọ ni o fọ́ àpáta tí omi tú jáde, tí odò sì ń ṣàn, ìwọ ni o sọ odò tí ń ṣàn di ilẹ̀ gbígbẹ. Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ náà sì ni òru, ìwọ ni o gbé òṣùpá ati oòrùn ró. Ìwọ ni o pa gbogbo ààlà ilẹ̀ ayé; ìwọ ni o dá ìgbà òjò ati ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn. OLUWA, ranti pé àwọn ọ̀tá ń fi ọ́ ṣe yẹ̀yẹ́; àwọn òmùgọ̀ eniyan sì ń fi orúkọ rẹ ṣe ẹlẹ́yà. Má fi ẹ̀mí àwa àdàbà rẹ lé àwọn ẹranko lọ́wọ́; má sì gbàgbé àwa eniyan rẹ tí ìyà ń jẹ títí lae. Ranti majẹmu rẹ; nítorí pé gbogbo kọ̀rọ̀ ilẹ̀ wa kún fún ìwà ipá. Má jẹ́ kí ojú ti àwọn tí à ń pọ́n lójú; jẹ́ kí àwọn tí ìyà ń jẹ ati àwọn aláìní máa yin orúkọ rẹ. Dìde Ọlọrun, gbèjà ara rẹ; ranti bí àwọn òmùgọ̀ eniyan tí ń fi ọ́ ṣe yẹ̀yẹ́ tọ̀sán-tòru. Má gbàgbé ariwo àwọn ọ̀tá rẹ; àní, igbe àwọn tí ó gbógun tì ọ́, tí wọn ń ké láìdá ẹnu dúró. A dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Ọlọrun; a dúpẹ́. À ń kéde orúkọ rẹ, a sì ń ròyìn iṣẹ́ ribiribi tí o ṣe. OLUWA ní, “Nígbà tí àkókò tí mo yà sọ́tọ̀ bá tó, n óo ṣe ìdájọ́ pẹlu àìṣojúṣàájú. Nígbà tí ayé bá ń mì síhìn-ín sọ́hùn-ún, ati gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀; èmi a mú kí òpó rẹ̀ dúró wámúwámú. Èmi a sọ fún àwọn tí ń fọ́nnu pé, ‘Ẹ yé fọ́nnu’; èmi a sì sọ fún àwọn eniyan burúkú pé, ‘Ẹ yé ṣe ìgbéraga.’ Ẹ má halẹ̀ ju bí ó ti yẹ lọ, ẹ má sì gbéraga.” Nítorí pé kì í ṣe láti ìlà oòrùn, tabi láti ìwọ̀ oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í ṣe apá gúsù tabi àríwá ni ìgbéga tií wá. Ọlọrun níí dájọ́ bí ó ti wù ú: á rẹ ẹnìkan sílẹ̀, á sì gbé ẹlòmíràn ga. Ife kan wà ní ọwọ́ OLUWA, Ibinu Oluwa ló kún inú rẹ̀, ó ń ru bí ọtí àní bí ọtí tí a ti lú, yóo ṣẹ́ ninu rẹ̀; gbogbo àwọn eniyan burúkú ilẹ̀ ayé ni yóo sì mu ún, wọn óo mu ún tán patapata tòun ti gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀. Ṣugbọn èmi óo máa yọ̀ títí lae, n óo kọ orin ìyìn sí Ọlọrun Jakọbu. Ọlọrun yóo gba gbogbo agbára ọwọ́ àwọn eniyan burúkú kúrò; ṣugbọn yóo fi agbára kún agbára fún àwọn olódodo. Àwọn ará Juda mọ Ọlọrun, orúkọ rẹ̀ sì lọ́wọ̀ ní Israẹli. Ilé rẹ̀ wà ní Salẹmu, ibùgbé rẹ̀ wà ní Sioni. Níbẹ̀ ni ó ti ṣẹ́ ọfà ọ̀tá tí ń rọ̀jò, ati apata, ati idà, ati àwọn ohun ìjà ogun. Ológo ni ọ́, ọlá rẹ sì pọ̀, ó ju ti àwọn òkè tí ó kún fún ẹran lọ. A gba ìkógun lọ́wọ́ àwọn akikanju, wọ́n sun oorun àsùn-ùn-jí; àwọn alágbára kò sì le gbé ọwọ́ láti jà. Nípa ìbáwí rẹ, Ọlọrun Jakọbu, ati ẹṣin, ati ẹni tó gun ẹṣin, gbogbo wọn ló ṣubú lulẹ̀, tí wọn kò sì lè mira. Ṣugbọn ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ni ọ́! Ta ló tó dúró níwájú rẹ tí ibinu rẹ bá dé? Láti ọ̀run wá ni o ti ń ṣe ìdájọ́, ẹ̀rù ba ayé, ayé sì dúró jẹ́ẹ́; nígbà tí Ọlọrun dìde láti gbé ìdájọ́ kalẹ̀, láti gba gbogbo àwọn tí à ń nilára láyé sílẹ̀. Dájúdájú ibinu eniyan yóo pada di ìyìn fún ọ; àwọn tí wọ́n bá sì bọ́ lọ́wọ́ ibinu rẹ yóo ṣe àjọ̀dún rẹ. Jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun rẹ, kí o sì mú un ṣẹ, kí gbogbo àwọn tí ó yí i ká mú ẹ̀bùn wá fún ẹni tí ó yẹ kí á bẹ̀rù. Ẹni tí ń gba ẹ̀mí àwọn ìjòyè, tí ó ń ṣe ẹ̀rù ba àwọn ọba ayé. Mo ké pe Ọlọrun fún ìrànlọ́wọ́, mo kígbe pe Ọlọrun kí ó lè gbọ́ tèmi. Ní ọjọ́ ìpọ́njú mi, mo wá OLUWA; ní òru, mo tẹ́wọ́ adura láìkáàárẹ̀, ṣugbọn n kò rí ìtùnú. Mo ronú nípa Ọlọrun títí, mò ń kérora; mo ṣe àṣàrò títí, ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì. OLUWA, o ò jẹ́ kí n dijú wò ní gbogbo òru mo dààmú tóbẹ́ẹ̀ tí n kò le sọ̀rọ̀. Mo ranti ìgbà àtijọ́, mo ranti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Mo ronú jinlẹ̀ lóru, mo ṣe àṣàrò, mo yẹ ọkàn mi wò. Ṣé Ọlọrun yóo kọ̀ wá sílẹ̀ títí lae ni; àbí inú rẹ̀ kò tún ní dùn sí wa mọ́? Ṣé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ti pin títí lae ni; àbí ìlérí rẹ̀ ti dópin patapata? Ṣé Ọlọrun ti gbàgbé láti máa ṣoore ni; àbí ó ti fi ibinu pa ojú àánú rẹ̀ dé? Nígbà náà ni mo wí pé, “Ohun tí ó bà mí lọ́kàn jẹ́ ni pé Ọ̀gá Ògo kò jẹ́wọ́ agbára mọ́.” N óo ranti àwọn iṣẹ́ OLUWA, àní, n óo ranti àwọn iṣẹ́ ìyanu ìgbàanì. N óo máa ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ; n óo sì máa ronú lórí àwọn iṣẹ́ ribiribi tí o ṣe. Ọlọrun, mímọ́ ni ọ̀nà rẹ; oriṣa wo ni ó tó Ọlọrun wa? Ìwọ ni Ọlọrun tí ń ṣe ohun ìyanu; o ti fi agbára rẹ hàn láàrin àwọn eniyan. O ti fi agbára rẹ gba àwọn eniyan rẹ là; àní, àwọn ọmọ Jakọbu ati Josẹfu. Nígbà tí omi òkun rí ọ, Ọlọrun, àní, nígbà tí omi òkun fi ojú kàn ọ́, ẹ̀rù bà á; ibú omi sì wárìrì. Ìkùukùu da omi òjò sílẹ̀, ojú ọ̀run sán ààrá; mànàmáná ń kọ yẹ̀rì káàkiri. Ààrá ń sán kíkankíkan ní ojú ọ̀run, mànàmáná ń kọ yànràn, gbogbo ayé sì mọ́lẹ̀; ilẹ̀ ayé wárìrì, ó sì mì tìtì. Ọ̀nà rẹ wà lójú omi òkun, ipa ọ̀nà rẹ la omi òkun ńlá já; sibẹ ẹnìkan kò rí ipa ẹsẹ̀ rẹ. O kó àwọn eniyan rẹ jáde bí agbo ẹran, o fi Mose ati Aaroni ṣe olórí wọn. Ẹ̀yin eniyan mi, ẹ dẹtí sí ẹ̀kọ́ mi; ẹ tẹ́tí si ọ̀rọ̀ ẹnu mi. N óo la ẹnu mi tòwe-tòwe; n óo fa ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ àtijọ́ yọ, ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀, ohun tí àwọn baba ńlá wa ti sọ fún wa. A kò ní fi pamọ́ fún àwọn ọmọ wọn; a óo máa sọ ọ́ fún àwọn ìran tí ń bọ̀ lẹ́yìn— iṣẹ́ ńlá OLUWA ati ìṣe akọni rẹ̀, ati iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe. Ó fi ìlànà lélẹ̀ fún ìdílé Jakọbu; ó gbé òfin kalẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli. Ó pa á láṣẹ fún àwọn baba ńlá wa, pé kí wọ́n fi kọ́ àwọn ọmọ wọn. Kí àwọn ìran tí ń bọ̀ lè mọ̀ ọ́n, àní, àwọn ọmọ tí a kò tíì bí, kí àwọn náà ní ìgbà tiwọn lè sọ ọ́ fún àwọn ọmọ wọn. Kí wọn lè gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun, kí wọn má gbàgbé iṣẹ́ rẹ̀, kí wọn sì máa pa òfin rẹ̀ mọ́, kí wọn má dàbí àwọn baba ńlá wọn, ìran àwọn olóríkunkun ati ọlọ̀tẹ̀, àwọn tí ọkàn wọn kò dúró ṣinṣin, tí ẹ̀mí wọn kò sì dúró gbọningbọnin ti Olodumare. Àwọn ọmọ Efuraimu kó ọrun, wọ́n kó ọfà, ṣugbọn wọ́n pẹ̀yìndà lọ́jọ́ ìjà. Wọn kò pa majẹmu Ọlọrun mọ́, wọ́n kọ̀, wọn kò jẹ́ pa òfin rẹ̀ mọ́. Wọ́n gbàgbé iṣẹ́ rẹ̀, ati iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe hàn wọ́n. Ní ìṣojú àwọn baba ńlá wọn, ó ṣe ohun ìyanu, ní ilẹ̀ Ijipti, ní oko Soani. Ó pín òkun níyà, ó jẹ́ kí wọ́n kọjá láàrin rẹ̀; ó sì mú kí omi nàró bí òpó ńlá. Ó fi ìkùukùu ṣe atọ́nà wọn ní ọ̀sán, ó fi ìmọ́lẹ̀ iná tọ́ wọn sọ́nà ní gbogbo òru. Ó la àpáta ni aṣálẹ̀, ó sì fún wọn ní omi mu lọpọlọpọ bí ẹni pé láti inú ibú. Ó mú ìṣàn omi jáde láti inú àpáta; ó sì mú kí ó ṣàn bí odò. Sibẹsibẹ wọn ò dẹ́kun ẹ̀ṣẹ̀ dídá; wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá Ògo ninu aṣálẹ̀. Wọ́n dán Ọlọrun wò ninu ọkàn wọn, wọ́n ń wá oúnjẹ tí yóo tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn. Wọ́n sọ̀rọ̀ ìwọ̀sí sí Ọlọrun, wọ́n ní, “Ṣé Ọlọrun lè gbé oúnjẹ kalẹ̀ fún wa ninu aṣálẹ̀? Lóòótọ́ ó lu òkúta tí omi fi tú jáde, tí odò sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn. Ṣé ó lè fún wa ní òkèlè pẹlu, àbí ó lè pèsè ẹran fún àwọn eniyan rẹ̀?” Nítorí náà nígbà tí OLUWA gbọ́, inú bí i; iná mọ́ ìdílé Jakọbu, inú OLUWA sì ru sí àwọn ọmọ Israẹli; nítorí pé wọn kò gba Ọlọrun gbọ́; wọn kò sì gbẹ́kẹ̀lé agbára ìgbàlà rẹ̀. Sibẹ ó pàṣẹ fún ìkùukùu lókè, ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ọ̀run sílẹ̀. Ó rọ òjò mana sílẹ̀ fún wọn láti jẹ, ó sì fún wọn ní ọkà ọ̀run. Ọmọ eniyan jẹ lára oúnjẹ àwọn angẹli; Ọlọrun fún wọn ní oúnjẹ àjẹtẹ́rùn. Ó mú kí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn fẹ́ ní ojú ọ̀run, ó sì fi agbára rẹ̀ darí afẹ́fẹ́ ìhà gúsù; ó sì rọ̀jò ẹran sílẹ̀ fún wọn bí erùpẹ̀ ilẹ̀; àní, ẹyẹ abìyẹ́ bíi yanrìn etí òkun. Ó mú kí wọn bọ́ sílẹ̀ láàrin ibùdó; yíká gbogbo àgọ́ wọn, Àwọn eniyan náà jẹ, wọ́n sì yó; nítorí pé Ọlọrun fún wọn ní ohun tí ọkàn wọn fẹ́. Ṣugbọn kí wọn tó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn, àní, nígbà tí wọn ṣì ń jẹun lọ́wọ́. Ọlọrun bínú sí wọn; ó pa àwọn tí ó lágbára jùlọ ninu wọn, ó sì lu àṣàyàn àwọn ọdọmọkunrin Israẹli pa. Sibẹsibẹ wọ́n tún dẹ́ṣẹ̀; pẹlu gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, wọn kò gbàgbọ́. Nítorí náà ó mú kí ọjọ́ ayé wọn pòórá bí afẹ́fẹ́; wọ́n sì lo ọjọ́ ayé wọn pẹlu ìjayà. Nígbàkúùgbà tí ó bá ń pa wọ́n, wọn á wá a; wọn á ronupiwada, wọn á sì wá Ọlọrun tọkàntọkàn. Wọn á ranti pé Ọlọrun ni àpáta ààbò wọn, ati pé Ọ̀gá Ògo ni olùràpadà wọn. Ṣugbọn wọn kàn ń fi ẹnu wọn pọ́n ọn ni; irọ́ ni wọ́n sì ń pa fún un. Ọkàn wọn kò dúró ṣinṣin lọ́dọ̀ rẹ̀; wọn kò sì pa majẹmu rẹ̀ mọ́. Sibẹ, nítorí pé aláàánú ni, ó dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, kò sì pa wọ́n run; ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó dáwọ́ ibinu rẹ̀ dúró, tí kò sì fi gbogbo ara bínú sí wọn. Ó ranti pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n, afẹ́fẹ́ lásán tí ń fẹ́ kọjá lọ, tí kò sì ní pada mọ́. Ìgbà mélòó ni wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i ninu ijù, tí wọ́n sì bà á lọ́kàn jẹ́ ninu aṣálẹ̀! Wọ́n dán an wò léraléra, wọ́n sì mú Ẹni Mímọ́ Israẹli bínú. Wọn kò ranti agbára rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ranti ọjọ́ tí ó rà wọ́n pada lọ́wọ́ ọ̀tá; nígbà tí ó ṣe iṣẹ́ abàmì ní ilẹ̀ Ijipti, tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ní oko Soani. Ó sọ omi odò wọn di ẹ̀jẹ̀, tí wọn kò fi lè mu omi wọn. Ó rán ọ̀wọ́ eṣinṣin sí wọn tí ó jẹ wọ́n, ati ọ̀pọ̀lọ́ tí ó pa wọ́n run. Ó mú kí kòkòrò jẹ èso ilẹ̀ wọn; eṣú sì jẹ ohun ọ̀gbìn wọn. Ó fi yìnyín ba àjàrà wọn jẹ́; ó sì fi òjò dídì run igi Sikamore wọn. Ó fi yìnyín pa mààlúù wọn; ó sì sán ààrá pa agbo aguntan wọn. Ó tú ibinu gbígbóná rẹ̀ lé wọn lórí: ìrúnú, ìkannú, ati ìpọ́njú, wọ́n dàbí ikọ̀ ìparun. Ó fi àyè gba ibinu rẹ̀; kò dá ẹ̀mí wọn sí, ó sì fi àjàkálẹ̀ àrùn pa wọ́n. O kọlu gbogbo àkọ́bí wọn ní ilẹ̀ Ijipti, àní, gbogbo àrẹ̀mọ ninu àgọ́ àwọn ọmọ Hamu. Lẹ́yìn náà, ó kó àwọn eniyan rẹ̀ jáde bí agbo ẹran ó sì dà wọ́n láàrin aṣálẹ̀ bí agbo aguntan. Ó dà wọ́n lọ láìléwu, ẹ̀rù kò bà wọ́n; òkun sì bo àwọn ọ̀tá wọn mọ́lẹ̀. Ó kó wọn wá sí ilẹ̀ mímọ́ rẹ̀, sí orí òkè tí ó ti fi agbára rẹ̀ gbà. Ó lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde kí wọn ó tó dé ibẹ̀; ó pín ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn bí ohun ìní; ó sì fi àwọn ọmọ Israẹli jókòó ninu àgọ́ wọn. Sibẹ, wọ́n dán Ọ̀gá Ògo wò, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí i; wọn kò tẹ̀lé ìlànà rẹ̀. Wọ́n yipada, wọ́n sì hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ bíi ti àwọn baba ńlá wọn; wọn kò ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, wọ́n dàbí ọfà tí ó tẹ̀. Wọ́n fi ojúbọ àwọn oriṣa wọn bí i ninu; wọ́n sì fi ère wọn mú un jowú. Nígbà tí Ọlọrun gbọ́, inú bí i gidigidi; ó sì kọ Israẹli sílẹ̀ patapata. Ó kọ ibùgbé rẹ̀ ní Ṣilo sílẹ̀, àní, àgọ́ rẹ̀ láàrin ọmọ eniyan. Ó jẹ́ kí á gbé àmì agbára rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn; ó sì fi ògo rẹ̀ lé ọ̀tá lọ́wọ́. Ó jẹ́ kí á fi idà pa àwọn eniyan rẹ̀; ó sì bínú gidigidi sí àwọn eniyan ìní rẹ̀. Iná run àwọn ọdọmọkunrin wọn; àwọn ọdọmọbinrin wọn kò sì rójú kọrin igbeyawo. Àwọn alufaa kú ikú ogun; àwọn opó wọn kò sì rójú sọkún. Lẹ́yìn náà, OLUWA dìde bí ẹni tají lójú oorun, bí ọkunrin alágbára tí ó mu ọtí yó tí ó ń kígbe. Ó lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ sẹ́yìn; ó dójú tì wọ́n títí ayé. Ó kọ àgọ́ àwọn ọmọ Josẹfu sílẹ̀; kò sì yan ẹ̀yà Efuraimu; ṣugbọn ó yan ẹ̀yà Juda, ó sì yan òkè Sioni tí ó fẹ́ràn. Níbẹ̀ ni ó kọ́ ibi mímọ́ rẹ̀ tí ó ga bí ọ̀run sí, ó sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ bí ayé títí lae. Ó yan Dafidi iranṣẹ rẹ̀; ó sì mú un láti inú agbo ẹran. Ó mú un níbi tí ó ti ń tọ́jú àwọn aguntan tí ó lọ́mọ lẹ́yìn, kí ó lè máa tọ́jú àwọn ọmọ Jakọbu, eniyan rẹ̀, àní àwọn ọmọ Israẹli, eniyan ìní rẹ̀. Ó tọ́jú wọn pẹlu òdodo, ó sì tọ́ wọn pẹlu ìmọ̀. Ọlọrun, àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà ti wọ inú ilẹ̀ ìní rẹ; wọ́n ti ba ilé mímọ́ rẹ jẹ́; wọ́n sì ti sọ Jerusalẹmu di ahoro. Wọ́n ti fi òkú àwọn iranṣẹ rẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run jẹ; wọ́n sì ti sọ òkú àwọn eniyan mímọ́ rẹ di ìjẹ fún àwọn ẹranko ìgbẹ́. Wọ́n ti da ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ bí omi, káàkiri Jerusalẹmu; kò sì sí ẹni tí yóo gbé wọn sin. A ti di ẹni ẹ̀gàn lójú àwọn aládùúgbò wa; àwọn tí ó yí wa ká ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́; wọ́n sì ń fi wá rẹ́rìn-ín. Yóo ti pẹ́ tó, OLUWA? Ṣé títí ayé ni o óo máa bínú ni? Àbí owú rẹ yóo máa jó bí iná? Tú ibinu rẹ sórí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò mọ̀ ọ́, ati orí àwọn ìjọba tí kò sìn ọ́. Nítorí pé wọ́n ti jẹ Jakọbu run; wọ́n sì ti sọ ibùgbé rẹ di ahoro. Má gbẹ̀san ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wa lára wa; yára, kí o ṣàánú wa, nítorí pé a ti rẹ̀ wá sílẹ̀ patapata. Ràn wá lọ́wọ́, Ọlọrun Olùgbàlà wa, nítorí iyì orúkọ rẹ; gbà wá, sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, nítorí orúkọ rẹ. Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè yóo fi máa sọ pé, “Níbo ni Ọlọrun wọn wà?” Níṣojú wa, gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn iranṣẹ rẹ tí a pa lára àwọn orílẹ̀-èdè! Jẹ́ kí ìkérora àwọn ìgbèkùn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ; gẹ́gẹ́ bí agbára ńlá rẹ, dá àwọn tí a dájọ́ ikú fún sí. OLUWA, san ẹ̀san ẹ̀gàn tí àwọn aládùúgbò wa gàn ọ́, san án fún wọn ní ìlọ́po meje, Nígbà náà, àwa eniyan rẹ, àní, àwa agbo aguntan pápá rẹ, yóo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ títí lae; a óo sì máa sọ̀rọ̀ ìyìn rẹ láti ìran dé ìran. Dẹtí sílẹ̀, ìwọ olùṣọ́-aguntan Israẹli, Ìwọ tí ò ń tọ́jú àwọn ọmọ Josẹfu bí agbo ẹran. Ìwọ tí o gúnwà láàrin àwọn kerubu, yọ bí ọjọ́ níwájú Efuraimu ati Bẹnjamini ati Manase. Sọ agbára rẹ jí, kí o sì wá gbà wá là. Mú wa bọ̀ sípò, Ọlọrun; fi ojurere wò wá, kí á le gbà wá là. OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, yóo ti pẹ́ tó, tí o óo máa bínú sí adura àwọn eniyan rẹ? O ti fi omijé bọ́ wọn bí oúnjẹ, o sì ti fún wọn ní omijé mu ní àmuyó. O ti mú kí àwọn aládùúgbò wa máa jìjàdù lórí wa; àwọn ọ̀tá wa sì ń fi wá rẹ́rìn-ín láàrin ara wọn. Mú wa bọ̀ sípò, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun; fi ojurere wò wá, kí á lè là. O mú ìtàkùn àjàrà kan jáde láti Ijipti; o lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde, o sì gbìn ín. O ro ilẹ̀ fún un; ó ta gbòǹgbò wọlẹ̀, igi rẹ̀ sì gbilẹ̀. Òjìji rẹ̀ bo àwọn òkè mọ́lẹ̀, ẹ̀ka rẹ sì bo àwọn igi kedari ńláńlá; àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tàn kálẹ̀ títí kan òkun, àwọn èèhù rẹ̀ sì kan odò ńlá. Kí ló dé tí o fi wó ògiri ọgbà rẹ̀, tí gbogbo àwọn tí ń kọjá lọ sì fi ń ká èso rẹ̀? Àwọn ìmàdò inú ìgbẹ́ ń jẹ ẹ́ ní àjẹrun, gbogbo àwọn nǹkan tí ń káàkiri ninu oko sì ń jẹ ẹ́. Jọ̀wọ́ tún yipada, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun! Bojúwolẹ̀ láti ọ̀run, kí o sì wò ó; kí o sì tọ́jú ìtàkùn àjàrà yìí, ohun ọ̀gbìn tí o fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbìn, àní, ọ̀dọ́ igi tí o fi ọwọ́ ara rẹ tọ́jú. Àwọn ọ̀tá ti dáná sun ún, wọ́n ti gé e lulẹ̀; fi ojú burúkú wò wọ́n, kí wọ́n ṣègbé! Ṣugbọn di ẹni tí o fúnra rẹ yàn mú, àní, ọmọ eniyan, tí o fúnra rẹ sọ di alágbára. Ṣe bẹ́ẹ̀, a kò sì ní pada lẹ́yìn rẹ; dá wa sí, a ó sì máa sìn ọ́! Mú wa bọ̀ sípò, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun! Fi ojurere wò wá, kí á lè là! Ẹ kọ orin sókè sí Ọlọrun, agbára wa; ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọrun Jakọbu. Ẹ dárin, ẹ lu samba, ẹ ta hapu dídùn ati lire. Ẹ fọn fèrè ní ọjọ́ oṣù titun, ati ní ọjọ́ oṣù tí a yà sọ́tọ̀, ati ní ọjọ́ àsè. Nítorí pé àṣẹ ni, fún àwọn ọmọ Israẹli, ìlànà sì ni, láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Jakọbu. Ó pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Josẹfu, nígbà tí ó kọlu ilẹ̀ Ijipti. Mo gbọ́ ohùn kan tí n kò gbọ́ rí: tí ó wí pé, “Mo ti sọ àjàgà náà kalẹ̀ lọ́rùn rẹ; mo ti gba agbọ̀n ẹrù kúrò lọ́wọ́ rẹ. Ninu ìnira, o ké pè mí, mo sì gbà ọ́; mo dá ọ lóhùn ninu ìjì ààrá, níbi tí mo fara pamọ́ sí; mo sì dán ọ wò ninu omi odò Meriba. Ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan mi, nígbà tí mo bá ń kìlọ̀ fun yín, àní kí ẹ fetí sílẹ̀ sí mi, ẹ̀yin ọmọ Israẹli! Kò gbọdọ̀ sí ọlọrun àjèjì kan kan láàrin yín; ẹ kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún oriṣa-koriṣa kan. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti. Ẹ ya ẹnu yín dáradára, n óo sì bọ yín ní àbọ́yó. “Ṣugbọn àwọn eniyan mi kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, Israẹli kò sì gba tèmi. Nítorí náà mo fi wọ́n sílẹ̀ sinu agídí ọkàn wọn, kí wọn máa ṣe ohun tó wù wọ́n. Àwọn eniyan mi ìbá jẹ́ gbọ́ tèmi, àní Israẹli ìbá jẹ́ máa rìn ní ọ̀nà mi! Kíákíá ni èmi ìbá kọjú ìjà sí àwọn ọ̀tá wọn, tí ǹ bá sì ṣẹgun wọn. Àwọn tí ó kórìíra OLUWA yóo fi ìbẹ̀rùbojo tẹríba fún un, ìyà óo sì jẹ wọ́n títí lae. Ṣugbọn èmi ó máa fi ọkà tí ó dára jùlọ bọ yín, n óo sì fi oyin inú àpáta tẹ yín lọ́rùn.” Ọlọrun ti jókòó ní ààyè rẹ̀ ninu ìgbìmọ̀ ọ̀run; ó sì ń ṣe ìdájọ́ láàrin àwọn ẹ̀dá ọ̀run: “Yóo ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin óo máa fi aiṣododo ṣe ìdájọ́, tí ẹ óo sì máa ṣe ojuṣaaju fún àwọn eniyan burúkú? Ẹ ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn ọmọ aláìníbaba; ẹ sì máa ṣe ẹ̀tọ́ fún àwọn tí ojú ń pọ́n ati àwọn talaka. Ẹ gba talaka ati aláìní sílẹ̀, ẹ gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú.” Wọn kò ní ìmọ̀ tabi òye, wọ́n ń rìn kiri ninu òkùnkùn, títí gbogbo ìpìlẹ̀ ayé fi mì tìtì. Mo ní, “oriṣa ni yín, gbogbo yín ni ọmọ Ọ̀gá Ògo. Ṣugbọn sibẹsibẹ, ẹ óo kú bí eniyan, ẹ ó sùn bí èyíkéyìí ninu àwọn ìjòyè.” Dìde, Ọlọrun, ṣe ìdájọ́ ayé, nítorí tìrẹ ni gbogbo orílẹ̀-èdè! Ọlọrun, má dákẹ́; má wòran; Ọlọrun má dúró jẹ́ẹ́! Wò ó! Àwọn ọ̀tá rẹ ń ṣọ̀tẹ̀ sí ọ; àwọn tí ó kórìíra rẹ sì ń yájú sí ọ. Wọ́n pète àrékérekè sí àwọn eniyan rẹ; wọ́n sì gbìmọ̀ pọ̀ sí àwọn tí ó sá di ọ́. Wọ́n ní, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á pa orílẹ̀-èdè wọn run; kí á má ranti orúkọ Israẹli mọ́!” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n jùmọ̀ pète pèrò; wọ́n dá majẹmu láti dojú kọ ọ́. Àwọn ará Edomu, ati àwọn ọmọ Iṣimaeli, àwọn ará Moabu, ati àwọn ọmọ Hagiri, àwọn ará Gebali, àwọn ọmọ Amoni, ati àwọn ọmọ Amaleki, àwọn ará Filistia ati àwọn tí ń gbé Tire. Àwọn ará Asiria pàápàá ti dara pọ̀ mọ́ wọn; àwọn ni alátìlẹ́yìn àwọn ọmọ Lọti. Ṣe wọ́n bí o ti ṣe àwọn ará Midiani, bí o ti ṣe Sisera ati Jabini ni odò Kiṣoni, àwọn tí o parun ní Endori, tí wọ́n di ààtàn lórí ilẹ̀. Ṣe àwọn ọlọ́lá wọn bí o ti ṣe Orebu ati Seebu; ṣe àwọn ìjòyè wọn bí o ti ṣe Seba ati Salumuna, àwọn tí ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á mú lára ilẹ̀ Ọlọrun kí á sọ ọ́ di tiwa.” Ọlọrun mi, ṣe wọ́n bí ààjà tíí ṣe ewé, àní, bí afẹ́fẹ́ tíí ṣe fùlùfúlù. Bí iná tíí jó igbó, àní, bí ọwọ́ iná sì ṣe ń jó òkè kanlẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ìjì rẹ lé wọn, kí o sì fi ààjà rẹ dẹ́rù bà wọ́n. Da ìtìjú bò wọ́n, kí wọn lè máa wá ọ kiri, OLUWA. Jẹ́ kí ojú tì wọ́n, kí ìdààmú dé bá wọn títí lae, kí wọn sì ṣègbé ninu ìtìjú. Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ìwọ nìkan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA, ni Ọ̀gá Ògo lórí gbogbo ayé. Ibùgbé rẹ lẹ́wà pupọ, OLUWA àwọn ọmọ ogun, ọkàn àgbàlá tẹmpili OLUWA ń fà mí, àárò rẹ̀ ń sọ mí; tọkàn-tara ni mo fi ń kọrin ayọ̀ sí Ọlọrun alààyè. Àwọn ẹyẹ ológoṣẹ́ pàápàá a máa kọ́ ilé, àwọn alápàáǹdẹ̀dẹ̀ a sì máa tẹ́ ìtẹ́ níbi tí wọ́n ń pa ọmọ sí, lẹ́bàá pẹpẹ rẹ, àní lẹ́bàá pẹpẹ rẹ, OLUWA àwọn ọmọ ogun, ọba mi, ati Ọlọrun mi. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń gbé inú ilé rẹ, wọn óo máa kọ orin ìyìn sí ọ títí lae! Ayọ̀ ń bẹ fún gbogbo àwọn tí ó fi ọ́ ṣe agbára wọn, tí ìrìn àjò sí Sioni jẹ wọ́n lógún. Bí wọ́n ti ń la àfonífojì Baka lọ, wọ́n ń sọ ọ́ di orísun omi; àkọ́rọ̀ òjò sì mú kí adágún omi kún ibẹ̀. Wọn ó máa ní agbára kún agbára, títí wọn ó fi farahàn níwájú Ọlọrun ní Sioni. OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, gbọ́ adura mi; tẹ́tí sílẹ̀, Ọlọrun Jakọbu! Bojú wo àpáta wa, Ọlọrun, fi ojú àánú wo ẹni àmì òróró rẹ. Nítorí pé ọjọ́ kan péré ninu àgbàlá rẹ, ṣe anfaani ju ẹgbẹrun ọjọ́ níbòmíràn lọ. Ó wù mí kí n jẹ́ aṣọ́nà ninu ilé Ọlọrun mi ju pé kí n máa gbé inú àgọ́ àwọn eniyan burúkú. Nítorí OLUWA Ọlọrun ni oòrùn ati ààbò wa, òun níí ṣeni lóore, tíí dáni lọ́lá, nítorí OLUWA kò ní rowọ́ láti fún ẹni tí ọkàn rẹ̀ mọ́ ní ohun tí ó dára. OLUWA àwọn ọmọ ogun, ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọ. OLUWA, o fi ojurere wo ilẹ̀ rẹ; o dá ire Jakọbu pada. O dárí àìdára àwọn eniyan rẹ jì wọ́n; o sì bo gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀. O mú ìrúnú rẹ kúrò; o dáwọ́ ibinu gbígbóná rẹ dúró. Tún mú wa bọ̀ sípò, Ọlọrun Olùgbàlà wa; dáwọ́ inú tí ń bí ọ sí wa dúró. Ṣé o óo máa bínú sí wa títí lae ni? Ṣé ibinu rẹ yóo máa tẹ̀síwájú láti ìran dé ìran ni? Ṣé o ò ní tún sọ wá jí ni, kí àwọn eniyan rẹ lè máa yọ̀ ninu rẹ? Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn wá, OLUWA; kí o sì fún wa ní ìgbàlà rẹ. Jẹ́ kí n gbọ́ ohun tí Ọlọrun, OLUWA yóo wí, nítorí pé ọ̀rọ̀ alaafia ni yóo sọ fún àwọn eniyan rẹ̀, àní, àwọn olùfọkànsìn rẹ̀, ṣugbọn kí wọn má yipada sí ìwà òmùgọ̀. Nítòótọ́, ìgbàlà rẹ̀ wà nítòsí fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀; kí ògo rẹ̀ lè wà ní ilẹ̀ wa. Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ yóo pàdé; òdodo ati alaafia yóo dì mọ́ ara wọn. Òtítọ́ yóo rú jáde láti inú ilẹ̀; òdodo yóo sì bojú wolẹ̀ láti ojú ọ̀run. Dájúdájú, OLUWA yóo fúnni ní ohun tí ó dára; ilẹ̀ wa yóo sì mú èso jáde lọpọlọpọ. Òdodo yóo máa rìn lọ níwájú rẹ̀, yóo sì sọ ipasẹ̀ rẹ̀ di ọ̀nà. Tẹ́tí sí mi OLUWA, kí o sì gbọ́ adura mi, nítorí òtòṣì ati aláìní ni mí. Dá ẹ̀mí mi sí nítorí olùfọkànsìn ni mí; gba èmi iranṣẹ rẹ tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ là; ìwọ ni Ọlọrun mi. Ṣàánú mi, OLUWA, nítorí ìwọ ni mò ń kígbe pè tọ̀sán-tòru. Mú inú iranṣẹ rẹ dùn, nítorí ìwọ ni mò ń gbadura sí. Nítorí pé olóore ni ọ́, OLUWA, o máa ń dárí jini; ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀ sí gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́. Fetí sí adura mi, OLUWA, gbọ́ igbe ẹ̀bẹ̀ mi. Ní ọjọ́ ìpọ́njú mo ké pè ọ́, nítorí pé o máa ń gbọ́ adura mi. OLUWA, kò sí èyí tí ó dàbí rẹ ninu àwọn oriṣa; kò sì sí iṣẹ́ ẹni tí ó dàbí iṣẹ́ rẹ. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí o dá ni yóo wá, OLUWA, wọn óo máa forí balẹ̀ níwájú rẹ: wọn óo sì máa yin orúkọ rẹ lógo. Nítorí pé o tóbi, o sì ń ṣe ohun ìyanu; ìwọ nìkan ni Ọlọrun. OLUWA, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, kí n lè máa rìn ninu òtítọ́ rẹ; kí n lè pa ọkàn pọ̀ láti máa bẹ̀rù orúkọ rẹ. Gbogbo ọkàn ni mo fi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, OLUWA, Ọlọrun mi; n óo máa yin orúkọ rẹ lógo títí lae. Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi sí mi; o ti yọ ọkàn mi kúrò ninu isà òkú. Ọlọrun, àwọn agbéraga dìde sí mi; ẹgbẹ́ àwọn ìkà, aláìláàánú kan ń lépa ẹ̀mí mi; wọn kò sì bìkítà fún ọ. Ṣugbọn ìwọ, OLUWA, ni Ọlọrun aláàánú ati olóore; o kì í tètè bínú, o sì kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́. Kọjú sí mi, kí o sì ṣàánú mi; fún èmi iranṣẹ rẹ ní agbára rẹ; kí o sì gba èmi ọmọ iranṣẹbinrin rẹ là. Fi àmì ojurere rẹ hàn mí, kí àwọn tí ó kórìíra mi lè rí i, kí ojú sì tì wọ́n; nítorí pé ìwọ, OLUWA, ni o ràn mí lọ́wọ́, tí o sì tù mí ninu. Ní orí òkè mímọ́ ni ìlú tí OLUWA tẹ̀dó wà. OLUWA fẹ́ràn ẹnubodè Sioni ju gbogbo ìlú yòókù lọ ní ilẹ̀ Jakọbu. Ọpọlọpọ nǹkan tó lógo ni a sọ nípa rẹ, ìwọ ìlú Ọlọrun. Tí mo bá ń ka àwọn ilẹ̀ tí ó mọ rírì mi, n óo dárúkọ Ijipti ati Babiloni, Filistia ati Tire, ati Etiopia. Wọn á máa wí pé, “Ní Jerusalẹmu ni wọ́n ti bí eléyìí.” A óo wí nípa Sioni pé, “Ibẹ̀ ni a ti bí eléyìí ati onítọ̀hún,” nítorí pé Ọ̀gá Ògo yóo fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀. OLUWA yóo ṣírò rẹ̀ mọ́ wọn nígbà tí ó bá ń ṣe àkọsílẹ̀ àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ní Sioni ni a ti bí eléyìí.” Àwọn akọrin ati àwọn afunfèrè ati àwọn tí ń jó yóo máa sọ pé, “Ìwọ, Sioni, ni orísun gbogbo ire wa.” OLUWA, Ọlọrun, Olùgbàlà mi, mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́ ní ọ̀sán; mo ké níwájú rẹ ní òru. Jẹ́ kí adura mi dé ọ̀dọ̀ rẹ; tẹ́tí sí igbe mi. Nítorí pé ọkàn mi kún fún ìyọnu; mo sì súnmọ́ isà òkú. Mo dàbí àwọn tí ó ń wọ ibojì lọ; mo dà bí ẹni tí kò lágbára mọ. N kò yàtọ̀ sí ẹni tí a pa tì sí apá kan láàrin àwọn òkú, mo dàbí ẹni tí a pa, tí ó sùn ninu ibojì, bí àwọn tí ìwọ kò ranti mọ́, nítorí pé wọ́n ti kúrò lábẹ́ ìtọ́jú rẹ. O ti fi mí sinu isà òkú tí ó jìn pupọ, ninu òkùnkùn, àní ninu ọ̀gbun. Ọwọ́ ibinu rẹ wúwo lára mi, ìgbì ìrúnú rẹ sì bò mí mọ́lẹ̀. O ti mú kí àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi fi mí sílẹ̀; mo sì ti di ẹni ìríra lọ́dọ̀ wọn: mo wà ninu àhámọ́, n kò sì lè jáde; ojú mi ti di bàìbàì nítorí ìbànújẹ́. Lojoojumọ ni mò ń ké pè ọ́, OLUWA; tí mò ń tẹ́wọ́ adura sí ọ. Ṣé òkú ni o óo ṣe iṣẹ́ ìyanu hàn? Ṣé àwọn òkú lè dìde kí wọ́n máa yìn ọ́? Ṣé a lè sọ̀rọ̀ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ninu ibojì? Àbí ẹnìkan lè sọ̀rọ̀ òtítọ́ rẹ ninu ìparun? Ṣé a lè rí iṣẹ́ ìyanu rẹ ninu òkùnkùn ikú? Àbí ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà rẹ wà ní ilẹ̀ àwọn tí a ti gbàgbé? Ṣugbọn OLUWA, èmi ń ké pè ọ́; ní òwúrọ̀ n óo gbadura sí ọ. OLUWA, kí ló dé tí o fi ta mí nù? Kí ló dé tí o fi ojú pamọ́ fún mi? Láti ìgbà èwe mi ni a tí ń jẹ mí níyà, tí mo sì fẹ́rẹ̀ kú, mo ti rí ìjẹníyà rẹ tí ó bani lẹ́rù; agara sì ti dá mi. Ìrúnú rẹ bò mí mọ́lẹ̀; ẹ̀rù rẹ sì bà mí dójú ikú. Wọ́n yí mi ká tọ̀sán-tòru bí ìṣàn omi ńlá; wọ́n ká mi mọ́ patapata. O ti mú kí ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi ati àwọn alábàárìn mi kọ̀ mí sílẹ̀; òkùnkùn nìkan ni ó yí mi ká níbi gbogbo. OLUWA, n óo máa kọrin ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ títí lae; n óo máa fi ẹnu mi kéde òtítọ́ rẹ láti ìran dé ìran. Nítorí pé, a ti fi ìdí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ múlẹ̀ títí lae; o sì ti fi ìdí òtítọ́ rẹ múlẹ̀ bí ojú ọ̀run. O sọ pé, “Mo ti dá majẹmu kan pẹlu ẹni tí mo yàn, mo ti búra fún Dafidi, iranṣẹ mi, pé, ‘N óo fi ìdí àwọn ọmọ rẹ múlẹ̀ títí lae, n óo sì gbé ìtẹ́ rẹ ró láti ìran dé ìran.’ ” Jẹ́ kí ojú ọ̀run máa kọrin ìyìn iṣẹ́ ìyanu rẹ, OLÚWA; kí àwọn eniyan mímọ́ sì máa kọrin ìyìn òtítọ́ rẹ. Nítorí ta ni a lè fi wé ọ ní ọ̀run, OLUWA? Ta ni ó dàbí OLUWA láàrin àwọn ẹ̀dá ọ̀run? Ọlọrun, ìwọ ni a bẹ̀rù ninu ìgbìmọ̀ àwọn eniyan mímọ́, o tóbi, o sì lẹ́rù ju gbogbo àwọn tí ó yí ọ ká lọ? OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, ta ló lágbára bíi rẹ? OLUWA, òtítọ́ rẹ yí ọ ká. Ò ń jọba lórí òkun tí ń ru; nígbà tí ìgbì rẹ̀ bá ru sókè, ìwọ ni ò ń mú kí ó rọlẹ̀. Ìwọ ni o wó Rahabu mọ́lẹ̀ bí òkú ẹran; o fi ọwọ́ agbára rẹ fọ́n àwọn ọ̀tá rẹ ká. Tìrẹ ni ọ̀run, tìrẹ sì ni ayé pẹlu; ìwọ ni o tẹ ayé ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ dó. Ìwọ ni o dá àríwá ati gúsù, òkè Tabori ati òkè Herimoni ń fi ayọ̀ yin orúkọ rẹ. Alágbára ni ọ́; agbára ń bẹ ní ọwọ́ rẹ; o gbé ọwọ́ agbára rẹ sókè. Òdodo ati ẹ̀tọ́ ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ; ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ ń lọ ṣiwaju rẹ. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó mọ ìhó ayọ̀ nnì, àwọn tí ń rìn ninu ìmọ́lẹ̀ ojurere rẹ, OLUWA, àwọn tí ń yọ̀ nítorí orúkọ rẹ tọ̀sán-tòru, tí sì ń gbé òdodo rẹ lárugẹ. Nítorí ìwọ ni ògo ati agbára wọn; nípa ojurere rẹ sì ni a ti ní ìṣẹ́gun. Dájúdájú, OLUWA, tìrẹ ni ààbò wa; ìwọ, Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ọba wa. Ní ìgbàanì, o sọ ninu ìran fún olùfọkànsìn rẹ pé, “Mo ti fi adé dé alágbára kan lórí, mo ti gbé ẹnìkan ga tí a yàn láàrin àwọn eniyan. Mo ti rí Dafidi, iranṣẹ mi; mo ti fi òróró mímọ́ mi yàn án; kí ọwọ́ agbára mi lè máa gbé e ró títí lae, kí ọwọ́ mi sì máa fún un ní okun. Ọ̀tá kan kò ní lè borí rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan burúkú kò ní tẹ orí rẹ̀ ba. N óo run ọ̀tá rẹ̀ níwájú rẹ̀; n óo sì bá àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ kanlẹ̀. Òtítọ́ mi ati ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ yóo wà pẹlu rẹ̀; orúkọ mi ni yóo sì máa fi ṣẹgun. N óo mú ìjọba rẹ̀ gbòòrò dé òkun; agbára rẹ̀ yóo sì tàn dé odò Yufurate Yóo ké pè mí pé, ‘Ìwọ ni Baba mi, Ọlọrun mi, ati Àpáta ìgbàlà mi.’ N óo fi ṣe àkọ́bí, àní, ọba tí ó tóbi ju gbogbo ọba ayé lọ. N óo máa fi ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ hàn án títí lae; majẹmu èmi pẹlu rẹ̀ yóo sì dúró ṣinṣin. Arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo máa jọba títí lae; ìtẹ́ rẹ̀ yóo sì máa bẹ níwọ̀n ìgbà tí ojú ọ̀run bá ń bẹ. “Bí àwọn ọmọ rẹ̀ bá kọ òfin mi sílẹ̀, tí wọn kò sì tẹ̀lé ìlànà mi, bí wọ́n bá tàpá sí àṣẹ mi, tí wọn kò sì pa òfin mi mọ́; n óo nà wọ́n lẹ́gba nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, n óo sì nà wọ́n ní pàṣán nítorí àìdára wọn. Ṣugbọn ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ kò ní kúrò lára rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní yẹ òtítọ́ mi. N kò ni yẹ majẹmu mi, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní yí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ pada. “Níwọ̀n ìgbà tí mo ti fi ìwà mímọ́ mi búra: n kò ní purọ́ fún Dafidi. Arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo máa jọba títí lae, ìtẹ́ rẹ̀ yóo sì máa wà níwájú mi, níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ń yọ. A óo fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ bí òṣùpá títí lae, yóo dúró ṣinṣin níwọ̀n ìgbà tí ojú ọ̀run bá ń bẹ.” Ṣugbọn nisinsinyii inú rẹ ti ru sí ẹni àmì òróró rẹ; o ti ta á nù, o sì ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀. O ti pa majẹmu tí o bá iranṣẹ rẹ dá tì, o ti ba adé rẹ̀ jẹ́, o ti fi wọ́lẹ̀. O ti wó gbogbo odi rẹ̀; o sì ti sọ ilé ìṣọ́ rẹ̀ di ahoro. Gbogbo àwọn tí ń kọjá lọ ní ń kó o lẹ́rù; ó ti di ẹni ẹ̀gàn lọ́dọ̀ àwọn aládùúgbò rẹ̀. O ti ran àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́; o ti mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ yọ̀ ọ́. Àní, o ti ba gbogbo ohun ìjà rẹ̀ jẹ́, o kò sì ràn án lọ́wọ́ lójú ogun. O ti gba ọ̀pá àṣẹ lọ́wọ́ rẹ̀; o sì ti wó ìtẹ́ rẹ̀ palẹ̀. O ti gé ìgbà èwe rẹ̀ kúrú; o sì ti da ìtìjú bò ó. Yóo ti pẹ́ tó, OLUWA? Ṣé títí lae ni o óo máa fi ara pamọ́ fún mi? Yóo ti pẹ́ tó tí ibinu rẹ yóo máa jò bí iná? OLUWA, ranti bí ọjọ́ ayé ẹ̀dá ti gùn mọ, ati pé ẹ̀dá lásán ni ọmọ eniyan! Ta ló wà láyé tí kò ní kú? Ta ló lè gba ẹ̀mí ara rẹ̀ lọ́wọ́ agbára isà òkú? OLUWA, níbo ni ìfẹ́ rẹ ìgbàanì tí kì í yẹ̀ wà, tí o búra fún Dafidi pẹlu òtítọ́ rẹ? OLUWA, ranti bí èmi, iranṣẹ rẹ, ti di ẹni yẹ̀yẹ́; ati bí mo ti ń farada ẹ̀gàn àwọn eniyan, OLUWA àwọn ọ̀tá rẹ ń fi ẹni tí o fi àmì òróró yàn ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n sì ń kẹ́gàn ìrìn ẹsẹ̀ rẹ̀. Ẹni ìyìn ni OLUWA títí lae! Amin! Amin! OLUWA, ìwọ ni o ti jẹ́ ibi ààbò wa láti ìrandíran. Kí o tó dá àwọn òkè, ati kí o tó dá ilẹ̀ ati ayé, láti ayérayé, ìwọ ni Ọlọrun. O sọ eniyan di erùpẹ̀ pada, o sì wí pé, “Ẹ yipada, ẹ̀yin ọmọ eniyan.” Nítorí pé lójú rẹ, ẹgbẹrun ọdún dàbí àná, tabi bí ìṣọ́ kan ní òru. Ìwọ a máa gbá ọmọ eniyan dànù; wọ́n dàbí àlá, bíi koríko tí ó tutù ní òwúrọ̀; ní òwúrọ̀ á máa gbilẹ̀, á sì máa jí pérépéré; ní ìrọ̀lẹ́ á sá, á sì rọ. Ibinu rẹ pa wá run; ìrúnú rẹ sì bò wá mọ́lẹ̀. O ti gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa kalẹ̀ ní iwájú rẹ; àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìkọ̀kọ̀ wa sì hàn kedere ninu ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ. Nítorí ọjọ́ ayé wa ń kọjá lọ ninu ibinu rẹ; ayé wa sì ń dópin bí ẹni mí kanlẹ̀. Aadọrin ọdún ni ọjọ́ ayé wa; pẹlu ipá a lè tó ọgọrin; sibẹ gbogbo rẹ̀ jẹ́ kìkì làálàá ati ìyọnu; kíá, ayé wa á ti dópin, ẹ̀mí wa á sì fò lọ. Ta ló mọ agbára ibinu rẹ? Ta ló sì mọ̀ pé bí ẹ̀rù rẹ ti tó bẹ́ẹ̀ ni ibinu rẹ rí? Nítorí náà kọ́ wa láti máa ka iye ọjọ́ orí wa, kí á lè kọ́gbọ́n. Yipada sí wa, OLUWA; yóo ti pẹ́ tó tí o óo máa bínú sí wa? Ṣàánú àwa iranṣẹ rẹ. Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn ní òwúrọ̀, kí á lè máa yọ̀, kí inú wa sì máa dùn ní gbogbo ọjọ́ ayé wa. Mú inú wa dùn fún iye ọjọ́ tí o ti fi pọ́n wa lójú, ati fún iye ọdún tí ojú wa ti fi rí ibi. Jẹ́ kí iṣẹ́ rẹ hàn sí àwọn iranṣẹ rẹ, kí agbára rẹ tí ó lógo sì hàn sí àwọn ọmọ wọn. Jẹ́ kí ojurere OLUWA Ọlọrun wa wà lára wa, fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀, jẹ́ kí iṣẹ́ ọwọ́ wa fi ìdí múlẹ̀. Ẹni tí ń gbé abẹ́ ààbò Ọ̀gá Ògo, tí ó wà lábẹ́ òjìji Olodumare, yóo wí fún OLUWA pé, “Ìwọ ni ààbò ati odi mi, Ọlọrun mi, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé.” Nítorí yóo yọ ọ́ ninu okùn àwọn pẹyẹpẹyẹ ati ninu àjàkálẹ̀ àrùn apanirun. Yóo da ìyẹ́ rẹ̀ bò ọ́, lábẹ́ ìyẹ́ apá rẹ̀ ni o óo ti rí ààbò; òtítọ́ rẹ̀ ni yóo jẹ́ asà ati apata rẹ. O ò ní bẹ̀rù ìdágìrì òru, tabi ọfà tí ń fò kiri ní ọ̀sán, tabi àjàkálẹ̀ àrùn tí ń jà kiri ninu òkùnkùn, tabi ìparun tí ń ṣeni lófò ní ọ̀sán gangan. Ẹgbẹrun lè ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ, tabi ẹgbaarun ni apá ọ̀tún rẹ; ṣugbọn kò ní súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ. Ojú nìkan ni óo kàn máa fi rí wọn, tí o óo sì máa fi wo èrè àwọn eniyan burúkú. Nítorí tí ìwọ ti fi OLUWA ṣe ààbò rẹ, o sì ti fi Ọ̀gá Ògo ṣe ibùgbé rẹ, ibi kankan kò ní dé bá ọ, bẹ́ẹ̀ ni àjálù kankan kò ní súnmọ́ ilé rẹ. Nítorí yóo pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀, nítorí rẹ, pé kí wọ́n máa pa ọ́ mọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ. Wọ́n óo fi ọwọ́ wọn gbé ọ sókè, kí o má baà fi ẹsẹ̀ gbún òkúta. O óo rìn kọjá lórí kinniun ati paramọ́lẹ̀; ẹgbọ̀rọ̀ kinniun ati ejò ńlá ni o óo fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀. OLUWA ní, “Nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ sí mi, n óo gbà á là; n óo dáàbò bò ó, nítorí pé ó mọ orúkọ mi. Yóo pè mí, n óo sì dá a lóhùn; n óo wà pẹlu rẹ̀ ninu ìṣòro, n óo yọ ọ́ ninu rẹ̀, n óo dá a lọ́lá. N óo fi ẹ̀mí gígùn tẹ́ ẹ lọ́rùn, n óo sì gbà á là.” Ó dára kí eniyan máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, OLUWA; kí ó sì máa kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ, ìwọ Ọ̀gá Ògo; ó dára kí eniyan máa kéde ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ní òwúrọ̀, kí ó máa kéde òtítọ́ rẹ ní alẹ́, pẹlu orin, lórí ohun èlò orin olókùn mẹ́wàá, ati hapu. Nítorí ìwọ, OLUWA, ti mú inú mi dùn nípa iṣẹ́ rẹ; OLUWA, mò ń fi ayọ̀ kọrin nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ tóbi pupọ, OLÚWA! Èrò rẹ sì jinlẹ̀ pupọ! Òpè eniyan kò lè mọ̀, kò sì le yé òmùgọ̀: pé bí eniyan burúkú bá tilẹ̀ rú bíi koríko, tí gbogbo àwọn aṣebi sì ń gbilẹ̀, ó dájú pé ìparun ayérayé ni òpin wọn. Ṣugbọn ẹni àgbéga títí lae ni ọ́, OLUWA. Wò ó, OLUWA, àwọn ọ̀tá rẹ yóo parun; gbogbo àwọn aṣebi yóo sì fọ́n ká. Ṣugbọn o ti gbé mi ga, o ti fún mi lágbára bíi ti ẹfọ̀n; o ti da òróró dáradára sí mi lórí. Mo ti fi ojú mi rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi, mo sì ti fi etí mi gbọ́ ìparun àwọn ẹni ibi tí ó gbé ìjà kò mí. Àwọn olódodo yóo gbilẹ̀ bí igi ọ̀pẹ, wọn óo dàgbà bí igi kedari ti Lẹbanoni. Wọ́n dàbí igi tí a gbìn sí ilé OLUWA, tí ó sì ń dàgbà ninu àgbàlá Ọlọrun wa. Wọn á máa so èso títí di ọjọ́ ogbó wọn, wọn á máa lómi lára, ewé wọn á sì máa tutù nígbà gbogbo; láti fihàn pé olóòótọ́ ni OLUWA; òun ni àpáta mi, kò sì sí aiṣododo lọ́wọ́ rẹ̀. OLUWA jọba; ó gbé ọlá ńlá wọ̀ bí ẹ̀wù; OLUWA gbé ọlá ńlá wọ̀, ó sì di agbára ni àmùrè. Ó fi ìdí ayé múlẹ̀; kò sì ní yẹ̀ laelae. A ti fi ìdí ìjọba rẹ múlẹ̀ láti ìgbà laelae; láti ayérayé ni o ti wà. Ibú omi gbé ohùn wọn sókè, OLUWA, ibú omi gbé ohùn wọn sókè, ó sì ń sán bí ààrá. OLUWA lágbára lókè! Ó lágbára ju ariwo omi òkun lọ, ó lágbára ju ìgbì omi òkun lọ. Àwọn òfin rẹ kìí yipada, ìwà mímọ́ ni ó yẹ ilé rẹ títí lae, OLUWA. OLUWA, ìwọ Ọlọrun ẹ̀san, ìwọ Ọlọrun ẹ̀san, fi agbára rẹ hàn! Dìde, ìwọ onídàájọ́ ayé; san ẹ̀san èrè iṣẹ́ àwọn agbéraga fún wọn! OLUWA, yóo ti pẹ́ tó? Àní, yóo ti pẹ́ tó tí àwọn eniyan burúkú yóo máa ṣe jàgínní? Wọ́n ń fi ìgbéraga sọ̀rọ̀ jàbùjàbù, gbogbo àwọn aṣebi ní ń fọ́nnu. Wọ́n ń rún àwọn eniyan rẹ mọ́lẹ̀, OLUWA, wọ́n ń pọ́n àwọn eniyan rẹ lójú. Wọ́n ń pa àwọn opó ati àwọn àlejò, wọ́n sì ń pa àwọn aláìníbaba; wọ́n ń sọ pé, “OLUWA kò rí wa; Ọlọrun Jakọbu kò ṣàkíyèsí wa.” Ẹ jẹ́ kí ó ye yín, ẹ̀yin tí ẹ ya òpè jùlọ láàrin àwọn eniyan! Ẹ̀yin òmùgọ̀, nígbà wo ni ẹ óo gbọ́n? Ṣé ẹni tí ó dá etí, ni kò ní gbọ́ràn? Àbí ẹni tí ó dá ojú, ni kò ní ríran? Ṣé ẹni tí ń jẹ àwọn orílẹ̀-èdè níyà, ni kò ní jẹ yín níyà? Àbí ẹni tí ń fún eniyan ní ìmọ̀, ni kò ní ní ìmọ̀? OLUWA mọ èrò ọkàn ọmọ eniyan, ó mọ̀ pé afẹ́fẹ́ lásán ni. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí o bá báwí, OLUWA, tí o sì kọ́ ní òfin rẹ, kí ó lè sinmi lọ́wọ́ ọjọ́ ìṣòro, títí tí a ó fi gbẹ́ kòtò fún eniyan burúkú. Nítorí OLUWA kò ní kọ àwọn eniyan rẹ̀ sílẹ̀; kò ní ṣá àwọn eniyan ìní rẹ̀ tì; nítorí pé ìdájọ́ òtítọ́ yóo pada jẹ́ ìpín àwọn olódodo, àwọn olóòótọ́ yóo sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. Ta ni yóo bá mi dìde sí àwọn eniyan burúkú? Ta ni yóo bá mi dìde sí àwọn aṣebi? Bí kì í bá ṣe pé OLUWA ràn mí lọ́wọ́, ǹ bá ti dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní isà òkú. Nígbà tí mo rò pé, “Ẹsẹ̀ mi ti yọ̀,” OLUWA, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ni ó gbé mi ró. Nígbà tí àìbàlẹ̀ ọkàn mi pọ̀ pupọ, ìwọ ni o tù mí ninu, tí o dá mi lọ́kàn le. Ǹjẹ́ o lè ní àjọṣe pẹlu àwọn ìkà aláṣẹ, àwọn tí ń fi òfin gbé ìwà ìkà ró? Wọ́n para pọ̀ láti gba ẹ̀mí olódodo; wọ́n sì dá ẹjọ́ ikú fún aláìṣẹ̀. Ṣugbọn OLUWA ti di ibi ìsádi mi, Ọlọrun mi sì ti di àpáta ààbò mi. Yóo san ẹ̀san ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún wọn, yóo pa wọ́n run nítorí ìwà ìkà wọn. OLUWA Ọlọrun wa yóo pa wọ́n run. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á kọrin sí OLUWA; ẹ jẹ́ kí á hó ìhó ayọ̀ sí Olùdáàbòbò ati ìgbàlà wa! Ẹ jẹ́ kí á wá siwaju rẹ̀ pẹlu ọpẹ́; ẹ jẹ́ kí á fi orin ìyìn hó ìhó ayọ̀ sí i. Nítorí pé Ọlọrun tí ó tóbi ni OLUWA, ọba tí ó tóbi ni, ó ju gbogbo oriṣa lọ. Ìkáwọ́ rẹ̀ ni ọ̀gbun ilẹ̀ wà; gíga àwọn òkè ńlá wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ pẹlu. Tirẹ̀ ni òkun, nítorí pé òun ni ó dá a; ọwọ́ rẹ̀ ni ó sì fi dá ìyàngbẹ ilẹ̀. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á jọ́sìn, kí á tẹríba, ẹ jẹ́ kí á kúnlẹ̀ níwájú OLUWA, Ẹlẹ́dàá wa! Nítorí òun ni Ọlọrun wa, àwa ni eniyan rẹ̀, tí ó ń kó jẹ̀ káàkiri, àwa ni agbo aguntan rẹ̀. Bí ẹ bá gbọ́ ohùn rẹ̀ lónìí, ẹ má ṣe orí kunkun bí ẹ ti ṣe ní Meriba, ati bí ẹ ti ṣe ní ijọ́un ní Masa, ninu aṣálẹ̀ nígbà tí àwọn baba ńlá yín dán mi wò, tí wọ́n dẹ mí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti rí ohun tí mo ti ṣe rí. Fún ogoji ọdún gbáko ni ọ̀rọ̀ wọn fi sú mi, tí mo sọ pé, “Ọkàn àwọn eniyan wọnyi ti yapa, wọn kò sì bìkítà fún ìlànà mi.” Nítorí náà ni mo fi fi ibinu búra pé, wọn kò ní wọ inú ìsinmi mi. Ẹ kọ orin titun sí OLUWA; gbogbo ayé, ẹ kọ orin sí OLUWA. Ẹ kọ orin sí OLUWA, ẹ yin orúkọ rẹ̀; ẹ sọ nípa ìgbàlà rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́. Ẹ kéde ògo rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè; ẹ sọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrin àwọn eniyan. Nítorí OLUWA tóbi, ó yẹ kí á máa yìn ín lọpọlọpọ; ó sì yẹ kí á bẹ̀rù rẹ̀ ju gbogbo oriṣa lọ. Nítorí oriṣa lásán ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ń sìn, ṣugbọn OLUWA ni ó dá ọ̀run. Iyì ati ọlá ńlá ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀; agbára ati ẹwà kún inú ilé mímọ́ rẹ̀. Ẹ yin OLUWA, gbogbo ẹ̀yin aráyé; ẹ kókìkí ògo ati agbára rẹ̀. Ẹ fún OLUWA ní iyì tí ó tọ́ sí orúkọ rẹ̀, ẹ mú ọrẹ lọ́wọ́ wá sinu àgbàlá rẹ̀. Ẹ sin OLUWA ninu ẹwà ìwà mímọ́; gbogbo ayé, ẹ wárìrì níwájú rẹ̀. Ẹ wí láàrin àwọn orílẹ̀-èdè pé, “OLUWA jọba! A ti fi ìdí ayé múlẹ̀, kò sì ní yẹ̀ lae; OLUWA yóo fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan.” Jẹ́ kí inú ọ̀run ó dùn, sì jẹ́ kí ayé ó yọ̀; kí òkun ó hó, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀. Jẹ́ kí pápá oko ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ yọ̀. Nígbà náà ni gbogbo igi igbó yóo fi ayọ̀ kọrin, níwájú OLUWA, nítorí pé ó ń bọ̀; ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé. Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé; yóo sì fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan. OLUWA jọba, kí ayé ó yọ̀; jẹ́ kí inú ogunlọ́gọ̀ erékùṣù ó dùn. Ìkùukùu ati òkùnkùn biribiri ni ó yí i ká; òdodo ati ẹ̀tọ́ ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ̀. Iná ń jó lọ níwájú rẹ̀, ó sì ń jó àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́tùn-ún lósì. Mànàmáná rẹ̀ tan ìmọ́lẹ̀ sí ayé, ilẹ̀ ayé rí i, ó sì wárìrì. Àwọn òkè ńlá yọ́ bí ìda níwájú OLUWA, àní, níwájú OLUWA gbogbo ayé. Ojú ọ̀run ń kéde òdodo rẹ̀; gbogbo orílẹ̀-èdè sì ń wo ògo rẹ̀. Ojú ti gbogbo àwọn tí ń bọ oriṣa, àwọn tí ń fi ère lásánlàsàn yangàn; gbogbo oriṣa ní ń foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀. Àwọn ará Sioni gbọ́, inú wọn dùn. Àwọn ará ìlú Juda sì ń yọ̀, nítorí ìdájọ́ rẹ, OLUWA. Nítorí ìwọ OLUWA ni Ọ̀gá Ògo, o ju gbogbo ayé lọ, a gbé ọ ga ju gbogbo oriṣa lọ. Ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn OLUWA, ẹ kórìíra ibi; OLUWA á máa dá ẹ̀mí àwọn olùfọkànsìn rẹ̀ sí, a sì máa gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú. Ìmọ́lẹ̀ á máa tàn fún àwọn olódodo, ayọ̀ sì wà fún àwọn olótìítọ́ inú. Ẹ máa yọ̀ ninu OLUWA, ẹ̀yin olódodo, kí ẹ sì máa yin orúkọ mímọ́ rẹ̀. Ẹ kọ orin titun sí OLUWA, nítorí tí ó ti ṣe ohun ìyanu; agbára ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ati apá mímọ́ rẹ̀ ni ó fi ṣẹgun. OLUWA ti sọ ìṣẹ́gun rẹ̀ di mímọ̀, ó ti fi ìdáláre rẹ̀ hàn lójú àwọn orílẹ̀-èdè. Ó ranti ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́ rẹ̀ sí àwọn ọmọ Israẹli; gbogbo ayé ti rí ìṣẹ́gun Ọlọrun wa. Gbogbo ayé, ẹ hó ìhó ayọ̀ sí OLUWA; ẹ bú sí orin ayọ̀, kí ẹ sì kọ orin ìyìn. Ẹ fi hapu kọ orin ìyìn sí OLUWA, àní, hapu ati ohùn orin dídùn. Ẹ fun fèrè ati ìwo kí ẹ sì hó ìhó ayọ̀ níwájú OLUWA Ọba. Kí òkun ó hó, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀, kí ayé hó, ati àwọn tí ń gbé inú rẹ̀. Omi òkun, ẹ pàtẹ́wọ́; kí ẹ̀yin òkè sì fi ayọ̀ kọrin pọ̀ níwájú OLUWA, nítorí pé ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé. Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé; yóo sì fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan. OLUWA jọba, kí àwọn orílẹ̀-èdè wárìrì; ó gúnwà lórí àwọn kerubu; kí ilẹ̀ mì tìtì. OLUWA tóbi ní Sioni, ó sì jọba lórí gbogbo orílẹ̀-èdè. Jẹ́ kí wọ́n yin orúkọ rẹ tí ó tóbi tí ó sì lẹ́rù, mímọ́ ni OLUWA! Ọba alágbára, ìwọ tí o fẹ́ràn òdodo, o ti fi ìdí ẹ̀tọ́ múlẹ̀; o ti dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ ati òdodo ní ilẹ̀ Jakọbu. Ẹ yin OLUWA, Ọlọrun wa, ẹ jọ́sìn níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀; mímọ́ ni OLUWA! Mose ati Aaroni wà lára àwọn alufaa rẹ̀; Samuẹli pàápàá wà lára àwọn tí ń pe orúkọ rẹ̀; wọ́n ké pe OLUWA ó sì dá wọn lóhùn. Ó bá wọn sọ̀rọ̀ ninu ọ̀wọ̀n ìkùukùu; wọ́n pa òfin rẹ̀ mọ́; wọ́n sì tẹ̀lé ìlànà tí ó fún wọn. OLUWA Ọlọrun wa, o dá wọn lóhùn; Ọlọrun tíí dáríjì ni ni o jẹ́ fún wọn; ṣugbọn ó gbẹ̀san ìwàkiwà wọn. Ẹ yin OLUWA, Ọlọrun wa, kí ẹ sì jọ́sìn níbi òkè mímọ́ rẹ̀; nítorí pé mímọ́ ni OLUWA Ọlọrun wa. Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí OLUWA, gbogbo ilẹ̀ ayé. Ẹ fi ayọ̀ sin OLUWA. Ẹ wá siwaju rẹ̀ pẹlu orin ayọ̀. Ẹ mọ̀ dájú pé OLUWA ni Ọlọrun, òun ló dá wa, òun ló ni wá; àwa ni eniyan rẹ̀, àwa sì ni agbo aguntan rẹ̀. Ẹ wọ ẹnubodè rẹ̀ tẹ̀yin tọpẹ́, kí ẹ sì wọ inú àgbàlá rẹ̀ tẹ̀yin tìyìn. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, kí ẹ sì máa yin orúkọ rẹ̀. Nítorí OLUWA ṣeun; ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae, òtítọ́ rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran. N óo kọrin ìfẹ́ ati ìdájọ́ òdodo, OLUWA, ìwọ ni n óo máa kọrin ìyìn sí. N óo múra láti hu ìwà pípé pẹlu ọgbọ́n; nígbà wo ni o óo wá sọ́dọ̀ mi? N óo máa fi tọkàntọkàn rin ìrìn pípé ninu ilé mi. N kò ní gba nǹkan burúkú láyè níwájú mi. Mo kórìíra ìṣe àwọn tí wọ́n tàpá sí Ọlọrun. N kò sì ní bá wọn lọ́wọ́ sí nǹkankan. Èròkérò yóo jìnnà sí ọkàn mi, n kò sì ní ṣe ohun ibi kankan, Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ẹnìkejì rẹ̀ níbi, n óo pa á run, n kò sì ní gba alágbèéré ati onigbeeraga láàyè. N óo máa fi ojurere wo àwọn olóòótọ́ ní ilẹ̀ náà, kí wọ́n lè máa bá mi gbé; ẹni tí ó bá sì ń hu ìwà pípé ni yóo máa sìn mí. Ẹlẹ́tàn kankan kò ní gbé inú ilé mi; bẹ́ẹ̀ ni òpùrọ́ kankan kò ní dúró níwájú mi. Ojoojumọ ni n óo máa pa àwọn eniyan burúkú run ní ilẹ̀ náà, n óo lé gbogbo àwọn aṣebi kúrò ninu ìlú OLUWA. Gbọ́ adura mi, OLUWA; kí o sì jẹ́ kí igbe mi dé ọ̀dọ̀ rẹ. Má yọwọ́ lọ́ràn mi lọ́jọ́ ìṣòro! Dẹtí sí adura mi; kí o sì tètè dá mi lóhùn nígbà tí mo bá ké pè ọ́. Nítorí ọjọ́ ayé mi ń kọjá lọ bí èéfín, eegun mi gbóná bí iná ààrò. Ìdààmú bá ọkàn mi, mo rọ bíi koríko, tóbẹ́ẹ̀ tí mo gbàgbé láti jẹun. Nítorí igbe ìrora mi, mo rù kan eegun. Mo dàbí igúnnugún inú aṣálẹ̀, àní, bí òwìwí inú ahoro. Mo dùbúlẹ̀ láìlè sùn, mo dàbí ẹyẹ tí ó dá wà lórí òrùlé. Àwọn ọ̀tá ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ tọ̀sán-tòru, àwọn tí wọn ń pẹ̀gàn mi ń fi orúkọ mi ṣépè. Mò ń jẹ eérú bí oúnjẹ, mo sì ń mu omijé mọ́ omi nítorí ìrúnú ati ibinu rẹ; o gbé mi sókè, o sì jù mí nù. Ọjọ́ ayé mi ń lọ bí òjìji àṣáálẹ́, mo sì ń rọ bíi koríko. Bẹ́ẹ̀ sì ni ìwọ OLUWA gúnwà títí lae, ọlá rẹ sì wà láti ìran dé ìran. Ìwọ óo dìde, o óo sì ṣàánú Sioni, nítorí ó tó àkókò láti fi ojú àánú wò ó. Àkókò tí o dá tó. Nítorí àwọn òkúta rẹ̀ ṣe iyebíye lójú àwọn iranṣẹ rẹ, àánú rẹ̀ sì ṣeni bí ó tilẹ̀ ti wó dà sinu erùpẹ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa bẹ̀rù orúkọ OLUWA, gbogbo ọba ayé ni yóo sì máa bẹ̀rù ògo rẹ̀. Nítorí OLUWA yóo tún Sioni kọ́, yóo sì fara hàn ninu ògo rẹ̀. Yóo gbọ́ adura àwọn aláìní, kò sì ní kẹ́gàn ẹ̀bẹ̀ wọn. Kí ẹ kọ èyí sílẹ̀ fún ìran tí ń bọ̀, kí àwọn ọmọ tí a kò tíì bí lè máa yin OLUWA, pé OLUWA bojú wo ilẹ̀ láti òkè mímọ́ rẹ̀, láti ọ̀run ni ó ti bojú wo ayé; láti gbọ́ ìkérora àwọn ìgbèkùn, ati láti dá àwọn tí a dájọ́ ikú fún sílẹ̀. Kí á lè pòkìkí orúkọ OLUWA ní Sioni, kí á sì máa yìn ín lógo ní Jerusalẹmu, nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè bá péjọ tàwọn tọba wọn, láti sin OLUWA. Ó ti gba agbára mi ní àìpé ọjọ́, ó ti gé ọjọ́ ayé mi kúrú. Mo ní, “Áà! Ọlọrun mi, má mú mi kúrò láyé láìpé ọjọ́, ìwọ tí ọjọ́ ayé rẹ kò lópin.” Láti ìgbà laelae ni o ti fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, iṣẹ́ ọwọ́ rẹ sì ni ọ̀run. Wọn óo parẹ́ ṣugbọn ìwọ yóo wà títí lae; gbogbo wọn yóo gbó bí aṣọ, o óo pààrọ̀ wọn bí aṣọ; wọn yóo sì di ohun ìpatì. Ṣugbọn ìwọ wà bákan náà, ọjọ́ ayé rẹ kò sì lópin. Ọmọ àwọn iranṣẹ rẹ yóo ní ibùgbé; bẹ́ẹ̀ ni arọmọdọmọ wọn yóo fẹsẹ̀ múlẹ̀ níwájú rẹ. Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi, fi tinútinú yin orúkọ rẹ̀ mímọ́. Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi, má sì ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀, ẹni tí ó ń dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́, tí ó ń wo gbogbo àrùn rẹ sàn; ẹni tí ó ń yọ ẹ̀mí rẹ kúrò ninu ọ̀fìn, tí ó fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ati àánú dé ọ ládé. Ẹni tí ó ń fi ohun dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn, tí ó fi ń sọ agbára ìgbà èwe rẹ dọ̀tun bíi ti idì. OLUWA a máa dáni láre a sì máa ṣe ìdájọ́ òdodo fún gbogbo àwọn tí a ni lára. Ó fi ọ̀nà rẹ̀ han Mose, ó sì ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ han àwọn ọmọ Israẹli. Aláàánú ati olóore ni OLUWA, kì í tètè bínú, ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀. Kì í fi ìgbà gbogbo báni wí, bẹ́ẹ̀ ni ibinu rẹ̀ kì í pẹ́ títí ayé. Kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa, bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa bí àìdára wa. Nítorí bí ọ̀run ti jìnnà sí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ṣe tóbi tó sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Bí ìlà oòrùn ti jìnnà sí ìwọ oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni ó mú ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa. Bí baba ti máa ń ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA máa ń ṣàánú àwọn tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀. Nítorí ó mọ ẹ̀dá wa; ó ranti pé erùpẹ̀ ni wá. Ọjọ́ ayé ọmọ eniyan dàbí ti koríko, eniyan a sì máa gbilẹ̀ bí òdòdó inú igbó; ṣugbọn bí afẹ́fẹ́ bá ti fẹ́ kọjá lórí rẹ̀, á rẹ̀ dànù, ààyè rẹ̀ kò sì ní ranti rẹ̀ mọ́. Ṣugbọn títí ayé ni ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀, sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, òdodo rẹ̀ wà lára arọmọdọmọ wọn. Ó wà lára àwọn tí ó ń pa majẹmu rẹ̀ mọ́, tí wọn sì ń ranti láti pa òfin rẹ̀ mọ́. OLUWA ti gbé ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ lọ́run, ó sì jọba lórí ohun gbogbo. Ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin angẹli rẹ̀, ẹ̀yin alágbára tí ẹ̀ ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀, tí ẹ sì ń fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ẹ yin OLUWA gbogbo ẹ̀yin ọmọ ogun rẹ̀, ẹ̀yin iranṣẹ rẹ̀, tí ẹ̀ ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ẹ yin OLUWA, gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, níbi gbogbo ninu ìjọba rẹ̀. Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi. Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi, OLUWA, Ọlọrun mi, ó tóbi pupọ, ọlá ati iyì ni ó wọ̀ bí ẹ̀wù. Ó fi ìmọ́lẹ̀ bora bí aṣọ, ó ta ojú ọ̀run bí ẹni taṣọ. Ìwọ tí o tẹ́ àjà ibùgbé rẹ sórí omi, tí o fi ìkùukùu ṣe kẹ̀kẹ́ ogun rẹ, tí o sì ń lọ geere lórí afẹ́fẹ́. Ìwọ tí o fi ẹ̀fúùfù ṣe iranṣẹ, tí o sì fi iná ati ahọ́n iná ṣe òjíṣẹ́ rẹ. Ìwọ tí o gbé ayé kalẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ rẹ̀, tí kò sì le yẹ̀ laelae. O fi ibú omi bò ó bí aṣọ, omi sì borí àwọn òkè ńlá. Nígbà tí o bá wọn wí, wọ́n sá, nígbà tí o sán ààrá, wọ́n sá sẹ́yìn. Wọ́n ṣàn kọjá lórí òkè lọ sí inú àfonífojì, sí ibi tí o yàn fún wọn. O ti pa ààlà tí wọn kò gbọdọ̀ kọjá, kí wọn má baà tún bo ayé mọ́lẹ̀ mọ́. Ìwọ ni o mú kí àwọn orísun máa tú omi jáde ní àfonífojì; omi wọn sì ń ṣàn láàrin àwọn òkè. Ninu omi wọn ni gbogbo ẹranko tí ń mu, ibẹ̀ sì ni àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tí ń rẹ òùngbẹ. Lẹ́bàá orísun wọnyi ni àwọn ẹyẹ ń gbé, wọ́n sì ń kọrin lórí igi. Láti ibùgbé rẹ lókè ni o tí ń bomi rin àwọn òkè ńlá. Ilẹ̀ sì mu àmutẹ́rùn nípa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Ó ń mú kí koríko dàgbà fún àwọn ẹran láti jẹ, ati ohun ọ̀gbìn fún ìlò eniyan, kí ó lè máa mú oúnjẹ jáde láti inú ilẹ̀; ati ọtí waini tí ń mú inú eniyan dùn, ati epo tí ń mú ojú eniyan dán, ati oúnjẹ tí ń fún ara lókun. Àwọn igi OLUWA ń mu omi ní àmutẹ́rùn, àní àwọn igi kedari Lẹbanoni tí ó gbìn. Lórí wọn ni àwọn ẹyẹ ń tẹ́ ìtẹ́ wọn sí, àkọ̀ sì ń kọ́ ilé rẹ̀ sórí igi firi. Òkè gíga ni ilé ewúrẹ́ igbó, abẹ́ àpáta sì ni ibùgbé ehoro. O dá òṣùpá láti máa sàmì àkókò, oòrùn sì mọ àkókò wíwọ̀ rẹ̀. O mú kí òkùnkùn ṣú, alẹ́ sì lẹ́, gbogbo ẹranko ìgbẹ́ sì ń jẹ kiri. Àwọn ẹgbọ̀rọ̀ kinniun ń bú fún ìjẹ, wọ́n ń wo ojú Ọlọrun fún oúnjẹ. Nígbà tí oòrùn bá là, wọn á wọ́ lọ; wọn á lọ dùbúlẹ̀ sinu ihò wọn. Ọmọ eniyan á sì jáde lọ síbi iṣẹ́ rẹ̀, á lọ síbi làálàá rẹ̀ títí di àṣáálẹ́. OLUWA, ìyanu ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ! Ọgbọ́n ni o fi dá gbogbo wọn. Ayé kún fún àwọn ẹ̀dá rẹ. Ẹ wo òkun bí ó ti tóbi tí ó sì fẹ̀, ó kún fún ọ̀kẹ́ àìmọye ẹ̀dá, nǹkan abẹ̀mí kéékèèké ati ńláńlá. Ibẹ̀ ni ọkọ̀ ojú omi ń gbà lọ, ati Lefiatani tí o dá láti máa ṣeré ninu òkun. Ojú rẹ ni gbogbo wọn ń wò, fún ìpèsè oúnjẹ ní àkókò. Nígbà tí o bá fún wọn, wọn á kó o jọ, nígbà tí o bá la ọwọ́, wọn á jẹ ohun dáradára ní àjẹyó. Bí o bá fojú pamọ́, ẹ̀rù á bà wọ́n, bí o bá gba ẹ̀mí wọn, wọn á kú, wọn á sì pada di erùpẹ̀. Nígbà tí o rán ẹ̀mí rẹ jáde, wọ́n di ẹ̀dá alààyè, o sì sọ orí ilẹ̀ di ọ̀tun. Kí ògo OLUWA máa wà títí lae, kí OLUWA máa yọ̀ ninu iṣẹ́ rẹ̀. Ẹni tí ó wo ilẹ̀, tí ilẹ̀ mì tìtì, tí ó fọwọ́ kan òkè, tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yọ èéfín. N óo kọrin ìyìn sí OLUWA níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè. N óo máa kọrin ìyìn sí Ọlọrun mi, níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀mí mi bá ń bẹ. Kí àṣàrò ọkàn mi kí ó dùn mọ́ ọn ninu nítorí mo láyọ̀ ninu OLUWA. Kí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ parẹ́ lórí ilẹ̀ ayé, kí àwọn eniyan burúkú má sí mọ́. Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi! Yin OLUWA! Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, ẹ pe orúkọ rẹ̀, ẹ fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè. Ẹ kọrin sí i, ẹ kọ orin ìyìn sí i, ẹ sọ nípa gbogbo iṣẹ́ ribiribi rẹ̀. Ẹ máa fi orúkọ mímọ́ rẹ̀ yangàn, kí ọkàn àwọn tí ń wá OLUWA ó máa yọ̀. Ẹ wá ojurere OLUWA ati agbára rẹ̀, ẹ máa wá ojurere rẹ̀ nígbà gbogbo. Ẹ ranti iṣẹ́ ribiribi tí ó ti ṣe, ẹ ranti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ati ìdájọ́ rẹ̀. Ẹ̀yin ọmọ Abrahamu, iranṣẹ rẹ̀, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀. OLUWA ni Ọlọrun wa, ìdájọ́ rẹ̀ kárí gbogbo ayé. Títí lae ni ó ń ranti majẹmu rẹ̀, ó ranti àṣẹ tí ó pa fún ẹgbẹẹgbẹrun ìran, majẹmu tí ó bá Abrahamu dá, ìlérí tí ó fi ìbúra ṣe fún Isaaki, tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún Jakọbu gẹ́gẹ́ bí òfin, àní fún Israẹli gẹ́gẹ́ bíi majẹmu ayérayé, ó ní: “Ẹ̀yin ni n óo fi ilẹ̀ Kenaani fún, yóo jẹ́ ìpín yín tí ẹ óo jogún.” Nígbà tí wọ́n kéré ní iye, tí wọn kò tíì pọ̀ rárá, tí wọn sì jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ náà, tí wọn ń káàkiri láti orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè, láti ìjọba kan dé òmíràn, kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ni wọ́n lára, ó bá àwọn ọba wí nítorí wọn. Ó ní, “Ẹ kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ẹni àmì òróró mi, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe àwọn wolii mi níbi.” Nígbà kan, ó mú kí ìyàn jà ní ilẹ̀ náà: ó ṣẹ́ ọ̀pá oúnjẹ mọ́ wọn lẹ́nu. Ṣugbọn ó kọ́ rán ọkunrin kan ṣáájú wọn, Josẹfu, ẹni tí a tà lẹ́rú. Wọ́n so ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ mọ́ ọn lẹ́sẹ̀, wọ́n ti ọrùn rẹ̀ bọ irin, títí ìgbà tí ohun tí ó sọ fi ṣẹ, tí OLUWA sì jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ọba ranṣẹ pé kí wọ́n tú u sílẹ̀, aláṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè sì dá a sílẹ̀. Ó fi jẹ aláṣẹ ilé rẹ̀, ati alákòóso gbogbo nǹkan ìní rẹ̀; láti máa ṣe olórí àwọn ìjòyè rẹ̀, kí ó sì máa kọ́ àwọn àgbà ìlú ní ìmọ̀. Lẹ́yìn náà, Israẹli dé sí Ijipti, Jakọbu ṣe àtìpó ní ilẹ̀ Hamu. OLUWA mú kí àwọn eniyan rẹ̀ pọ̀ sí i, ó sì mú kí wọ́n lágbára ju àwọn ọ̀tá wọn lọ. Ó yí àwọn ará Ijipti lọ́kàn pada, tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi kórìíra àwọn eniyan rẹ̀, tí wọ́n sì hùwà àrékérekè sí àwọn iranṣẹ rẹ̀. Ó rán Mose, iranṣẹ rẹ̀, ati Aaroni, ẹni tí ó yàn. Wọ́n ṣe iṣẹ́ àmì rẹ̀ ní ilẹ̀ náà, wọ́n sì ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ní ilẹ̀ Hamu, Ọlọrun rán òkùnkùn, ilẹ̀ sì ṣú, ṣugbọn wọ́n ṣe oríkunkun sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀, ó sì mú kí ẹja wọn kú. Ọ̀pọ̀lọ́ ń tú jáde ní ilẹ̀ wọn, títí kan ìyẹ̀wù àwọn ọba wọn. Ọlọrun sọ̀rọ̀, eṣinṣin sì rọ́ dé, iná aṣọ sì bo gbogbo ilẹ̀ wọn. Ó rọ̀jò yìnyín lé wọn lórí, mànàmáná sì ń kọ káàkiri ilẹ̀ wọn. Ó kọlu àjàrà ati igi ọ̀pọ̀tọ́ wọn, ó sì wó àwọn igi ilẹ̀ wọn. Ó sọ̀rọ̀, àwọn eṣú sì rọ́ dé, ati àwọn tata tí kò lóǹkà; wọ́n jẹ gbogbo ewé tí ó wà ní ilẹ̀ wọn, ati gbogbo èso ilẹ̀ náà. Ó kọlu gbogbo àkọ́bí ilẹ̀ wọn, àní, gbogbo àrẹ̀mọ ilẹ̀ wọn. Lẹ́yìn náà, ó mú àwọn ọmọ Israẹli jáde, tàwọn ti fadaka ati wúrà, kò sì sí ẹnikẹ́ni ninu ẹ̀yà kankan tí ó ṣe àìlera. Inú àwọn ará Ijipti dùn nígbà tí wọ́n jáde, nítorí ẹ̀rù àwọn ọmọ Israẹli ń bà wọ́n. OLUWA ta ìkùukùu bò wọ́n, ó sì pèsè iná láti tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn lóru. Wọ́n bèèrè ẹran, ó fún wọn ní àparò, ó sì pèsè oúnjẹ àjẹtẹ́rùn fún wọn láti ọ̀run. Ó la àpáta, omi tú jáde, ó sì ṣàn ninu aṣálẹ̀ bí odò. Nítorí pé ó ranti ìlérí mímọ́ rẹ̀, ati Abrahamu, iranṣẹ rẹ̀. Ó fi ayọ̀ kó àwọn eniyan rẹ̀ jáde, ó kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jáde pẹlu orin. Ó fún wọn ní ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, wọ́n sì jogún èrè iṣẹ́ àwọn eniyan náà. Kí wọ́n lè máa mú àṣẹ rẹ̀ ṣẹ, kí wọ́n sì máa pa òfin rẹ̀ mọ́. Ẹ yin OLUWA! Ẹ yin OLUWA! Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ta ló lè sọ iṣẹ́ agbára OLUWA tán? Ta ló sì lè fi gbogbo ìyìn rẹ̀ hàn? Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń ṣe ẹ̀tọ́, àwọn tí ń ṣe ohun tí ó tọ̀nà nígbà gbogbo. Ranti mi, OLUWA, nígbà tí o bá ń ṣí ojurere wo àwọn eniyan rẹ. Ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí o bá ń gbà wọ́n là. Kí n lè rí ire àwọn àyànfẹ́ rẹ kí n lè ní ìpín ninu ayọ̀ àwọn eniyan rẹ, kí n sì lè máa ṣògo pẹlu àwọn tí ó jẹ́ eniyan ìní rẹ. A ti ṣẹ̀, àtàwa, àtàwọn baba wa, a ti ṣe àìdára, a sì ti hùwà burúkú. Nígbà tí àwọn baba ńlá wa wà ní Ijipti, wọn kò náání iṣẹ́ ìyanu rẹ, wọn kò sì ranti bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ti pọ̀ tó. Ṣugbọn wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá Ògo lẹ́bàá òkun pupa. Sibẹsibẹ, ó gbà wọ́n là, nítorí orúkọ rẹ̀; kí ó lè fi títóbi agbára rẹ̀ hàn. Ó bá òkun pupa wí, òkun pupa gbẹ, ó sì mú wọn la ibú já bí ẹni rìn ninu aṣálẹ̀. Ó gbà wọ́n là lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra wọn, ó sì kó wọn yọ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn. Omi bo àwọn ọ̀tá wọn, ẹyọ ẹnìkan kò sì là. Nígbà náà ni wọ́n tó gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́, wọ́n sì kọrin yìn ín. Kò pẹ́ tí wọ́n tún fi gbàgbé iṣẹ́ rẹ̀, wọn kò sì dúró gba ìmọ̀ràn rẹ̀. Wọ́n ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ní aṣálẹ̀, wọ́n sì dán Ọlọrun wò. Ó fún wọn ní ohun tí wọ́n bèèrè, ṣugbọn ó fi àìsàn ajẹnirun ṣe wọ́n. Nígbà tí wọ́n ṣe ìlara sí Mose ninu ibùdó, ati sí Aaroni, ẹni mímọ́ OLÚWA. Ilẹ̀ yanu, ó gbé Datani mì, ó sì bo Abiramu ati àwọn tí ó tẹ̀lé e mọ́lẹ̀. Iná sọ láàrin wọn, ó sì jó àwọn eniyan burúkú náà run. Wọ́n yá ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù ní Horebu, wọ́n sì bọ ère tí wọ́n dà. Wọ́n gbé ògo Ọlọrun fún ère mààlúù tí ń jẹ koríko. Wọ́n gbàgbé Ọlọrun, Olùgbàlà wọn, tí ó ṣe iṣẹ́ ribiribi ní Ijipti, ó ṣe, iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Hamu, ati ohun ẹ̀rù lẹ́bàá òkun pupa. Nítorí náà ni ó ṣe wí pé òun yóo pa wọ́n run, bí kì í bá ṣe ti Mose, àyànfẹ́ rẹ̀, tí ó dúró níwájú rẹ̀, tí ó sì ṣìpẹ̀, láti yí ibinu OLUWA pada, kí ó má baà pa wọ́n run. Wọn kò bìkítà fún ilẹ̀ dáradára náà, wọn kò sì ní igbagbọ ninu ọ̀rọ̀ OLUWA. Wọ́n ń kùn ninu àgọ́ wọn, wọn kò sì fetí sí ohùn OLUWA. Nítorí náà, ó gbé ọwọ́ sókè, ó búra fún wọn pé òun yóo jẹ́ kí wọ́n kú sí aṣálẹ̀, ati pé òun yóo fọ́n àwọn ìran wọn káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè. Wọ́n da ara wọn pọ̀ mọ́ Baali ti Peori, wọ́n sì ń jẹ ẹbọ tí wọ́n rú sí òkú. Wọ́n fi ìwà burúkú wọn mú OLUWA bínú, àjàkálẹ̀ àrùn sì bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn. Nígbà náà ni Finehasi dìde, ó bẹ̀bẹ̀ fún wọn, àjàkálẹ̀ àrùn sì dáwọ́ dúró. A sì kà á kún òdodo fún un, láti ìrandíran títí lae. Wọ́n mú OLUWA bínú lẹ́bàá omi Meriba, wọ́n sì fi tiwọn kó bá Mose, nítorí wọ́n mú Mose bínú, ọ̀rọ̀ tí kò yẹ sì ti ẹnu rẹ̀ jáde. Wọn kò pa àwọn eniyan ilẹ̀ náà run, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún wọn, ṣugbọn wọ́n dara pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè náà, wọ́n sì kọ́ ìṣe wọn. Wọ́n bọ àwọn oriṣa wọn, èyí sì fa ìpalára fún wọn. Wọ́n fi àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin wọn bọ oriṣa. Wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, àní, ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkunrin, ati ti àwọn ọmọbinrin wọn, tí wọ́n fi bọ àwọn oriṣa ilẹ̀ Kenaani; wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ sọ ilẹ̀ náà di aláìmọ́. Nítorí náà, wọ́n fi ìṣe wọn sọ ara wọn di aláìmọ́, wọ́n sì sọ ara wọn di alágbèrè. Nígbà náà ni inú bí OLUWA sí àwọn eniyan rẹ̀, ó sì kórìíra àwọn ẹni ìní rẹ̀. Ó fi wọ́n lé àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn lọ́wọ́, títí tí àwọn tí ó kórìíra wọn fi jọba lé wọn lórí. Àwọn ọ̀tá wọn ni wọ́n lára, wọ́n sì fi agbára mú wọn sìn. Ọpọlọpọ ìgbà ni ó gbà wọ́n sílẹ̀, ṣugbọn wọ́n ti pinnu láti máa tàpá sí i, OLUWA sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Sibẹsibẹ, ninu ìnira wọn, ó ṣàánú wọn, nígbà tí ó gbọ́ igbe wọn. Nítorí tiwọn, ó ranti majẹmu tí ó dá, ó sì yí ìpinnu rẹ̀ pada nítorí ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀. Ó jẹ́ kí àánú wọn ṣe gbogbo àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn. Gbà wá, OLUWA, Ọlọrun wa, kí o sì kó wa kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, kí á lè máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ, kí á sì lè máa ṣògo ninu ìyìn rẹ. Ẹni ìyìn ni OLUWA, Ọlọrun Israẹli, lae ati laelae. Kí gbogbo eniyan máa wí pé, “Amin!” Ẹ yin OLUWA! Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun, nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Kí àwọn tí OLUWA ti rà pada kí ó wí bẹ́ẹ̀, àní, àwọn tí ó yọ kúrò ninu ìpọ́njú, tí ó kó wọn jáde kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀n-ọn-nì, láti ìhà ìlà oòrùn ati láti ìhà ìwọ̀ oòrùn, láti ìhà àríwá ati láti ìhà gúsù. Àwọn kan ń káàkiri ninu aṣálẹ̀, wọn kò sì rí ọ̀nà dé ìlú tí wọ́n lè máa gbé. Ebi pa wọ́n, òùngbẹ gbẹ wọ́n, ó sì rẹ̀ wọ́n wá láti inú. Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn, ó sì yọ wọ́n kúrò ninu ìṣẹ́ wọn. Ó kó wọn gba ọ̀nà tààrà jáde, lọ sí ìlú tí wọ́n lè máa gbé. Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, àní nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún àwọn ọmọ eniyan. Nítorí pé ó fi omi tẹ́ àwọn tí òùngbẹ ń gbẹ lọ́rùn, ó sì fi oúnjẹ dáradára bọ́ àwọn tí ebi ń pa ní àbọ́yó. Àwọn kan jókòó ninu òkùnkùn pẹlu ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn, wọ́n wà ninu ìgbèkùn ati ìpọ́njú, a sì fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè wọ́n, nítorí pé wọ́n tàpá sí òfin Ọlọrun, wọ́n sì pẹ̀gàn ìmọ̀ràn ọ̀gá ògo. Làálàá mú kí agara dá ọkàn wọn, wọ́n ṣubú lulẹ̀ láìsí olùrànlọ́wọ́. Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn, ó sì gbà wọ́n ninu ìṣẹ́ wọn. Ó yọ wọ́n kúrò ninu òkùnkùn ati ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn, ó sì já ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ wọn. Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, àní nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún eniyan. Nítorí pé ó fọ́ ìlẹ̀kùn idẹ, ó sì gé ọ̀pá ìdábùú irin ní àgéjá. Àwọn kan ninu wọn di òmùgọ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ojú sì pọ́n wọn nítorí àìdára wọn. Oúnjẹ rùn sí wọn, wọ́n sì súnmọ́ bèbè ikú. Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn, ó sì yọ wọ́n ninu ìṣẹ́ wọn. Ó sọ̀rọ̀, ó sì mú wọn lára dá, ó tún kó wọn yọ ninu ìparun. Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, àní, nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún eniyan. Kí wọn máa rú ẹbọ ọpẹ́, kí wọn sì máa fi orin ayọ̀ ròyìn iṣẹ́ rẹ̀. Àwọn kan wọ ọkọ̀ ojú omi, wọ́n ń ṣòwò lórí agbami òkun, wọ́n rí ìṣe OLUWA, àní iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ninu ibú. Ó pàṣẹ, ìjì líle sì bẹ̀rẹ̀ sí jà, tóbẹ́ẹ̀ tí ìgbì omi fi ru sókè. Àwọn ọkọ̀ ojú omi fò sókè roro, wọ́n sì tún já wá sílẹ̀ dòò, sinu ibú, jìnnìjìnnì bò wọ́n ninu ewu tí wọ́n wà. Wọ́n ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n káàkiri bí ọ̀mùtí, gbogbo ọgbọ́n sì parẹ́ mọ́ wọn ninu. Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn, ó sì yọ wọ́n ninu ìṣẹ́ wọn. Ó mú kí ìgbì dáwọ́ dúró, ó sì mú kí ríru omi òkun rọlẹ̀ wọ̀ọ̀. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ nígbà tí ilẹ̀ rọ̀, ó sì mú kí wọ́n gúnlẹ̀ sí èbúté ìfẹ́ wọn. Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, àní nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún eniyan. Kí wọn gbé e ga láàrin ìjọ eniyan, kí wọn sì yìn ín ní àwùjọ àwọn àgbà. Ó sọ odò di aṣálẹ̀, ó sọ orísun omi di ilẹ̀ gbígbẹ, ó sọ ilẹ̀ eléso di aṣálẹ̀ oníyọ̀, nítorí ìwà burúkú àwọn tí ń gbé inú rẹ̀. Ó sọ aṣálẹ̀ di adágún omi, ó sì sọ ilẹ̀ gbígbẹ di orísun omi. Ó jẹ́ kí àwọn tí ebi ń pa máa gbé ibẹ̀, wọ́n sì tẹ ìlú dó, láti máa gbé. Wọ́n dáko, wọ́n gbin àjàrà, wọ́n sì kórè lọpọlọpọ. Ó bukun wọn, ó mú kí wọn bí sí i lọpọlọpọ, kò sì jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn wọ́n dínkù. Nígbà tí wọ́n dínkù, tí a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, nípa ìnira, ìpọ́njú, ati ìṣòro, ó da ẹ̀gàn lu àwọn ìjòyè, ó sì mú kí wọn máa rìn kiri ní aṣálẹ̀, níbi tí kò sí ọ̀nà. Ṣugbọn ó yọ aláìní kúrò ninu ìpọ́njú, ó sì mú kí ìdílé wọn pọ̀ sí i bí agbo ẹran. Àwọn olódodo rí i, inú wọn dùn, a sì pa àwọn eniyan burúkú lẹ́nu mọ́. Kí ẹni tí ó gbọ́n kíyèsí nǹkan wọnyi; kí ó sì fi òye gbé ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀. Ọkàn mi dúró ṣinṣin, Ọlọrun ọkàn mi dúró ṣinṣin. N óo kọrin, n óo sì máa yìn ọ́. Jí, ìwọ ọkàn mi! Ẹ jí ẹ̀yin ohun èlò ìkọrin ati hapu! Èmi fúnra mi náà yóo jí ní òwúrọ̀ kutukutu, OLUWA, n óo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ láàrin àwọn eniyan, n óo sì máa kọrin ìyìn sí ọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè. Nítorí pé ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi, ó ga ju ọ̀run lọ, òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run. Kí á gbé ọ ga ju ọ̀run lọ, Ọlọrun, kí ògo rẹ sì kárí gbogbo ayé. Kí á lè gba àyànfẹ́ rẹ là, fi ọwọ́ agbára rẹ gbà wá, kí o sì dá mi lóhùn. Ọlọrun ti sọ̀rọ̀ ninu ilé mímọ́ rẹ̀, ó ní, “Tayọ̀tayọ̀ ni n óo fi pín Ṣekemu, n óo sì pín àfonífojì Sukotu. Tèmi ni Gileadi, tèmi sì ni Manase. Efuraimu ni àkẹtẹ̀ àṣíborí mi, Juda sì ni ọ̀pá àṣẹ mi. Moabu ni ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi, lórí Edomu ni n óo bọ́ bàtà mi lé, n óo sì hó ìhó ìṣẹ́gun lórí Filistia.” Ta ni yóo mú mi wọ inú ìlú olódi náà? Ta ni yóo mú mi lọ sí Edomu? Ọlọrun, o kò ha ti kọ̀ wá sílẹ̀? Ọlọrun, o ò bá àwọn ọmọ ogun wa lọ sójú ogun mọ́. Ràn wá lọ́wọ́, bá wa gbógun ti àwọn ọ̀tá wa, nítorí pé asán ni ìrànlọ́wọ́ eniyan. Pẹlu àtìlẹ́yìn Ọlọ́run, a óo ṣe akin; nítorí òun ni yóo tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀. Má dákẹ́, ìwọ Ọlọrun tí mò ń yìn. Nítorí pé ẹnu àwọn eniyan burúkú ati ti àwọn ẹlẹ́tàn kò dákẹ́, wọ́n ń sọ̀rọ̀ èké nípa mi. Wọ́n ń sọ ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ káàkiri nípa mi, wọ́n sì ń gbógun tì mí láìnídìí. Èmi fẹ́ràn wọn; ṣugbọn ẹ̀sùn ni wọ́n fi ń kàn mí, sibẹ, adura ni mò ń gbà fún wọn. Ibi ni wọ́n fí ń san oore fún mi, ìkórìíra ni wọ́n sì fi ń san ìfẹ́ tí mo ní sí wọn. Yan eniyan burúkú tì í, jẹ́ kí ẹlẹ́sùn èké kó o sẹ́jọ́. Nígbà tí a bá ń dá ẹjọ́ rẹ̀, jẹ́ kí wọn dá a lẹ́bi; kí ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ di ọ̀ràn sí i lọ́rùn. Ṣe é ní ẹlẹ́mìí kúkúrú, kí ohun ìní rẹ̀ di ti àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà. Kí àwọn ọmọ rẹ̀ di aláìníbaba, kí aya rẹ̀ di opó. Kí àwọn ọmọ rẹ̀ di alárìnká, kí wọn máa ṣagbe kiri; kí á lé wọn jáde kúrò ninu ahoro tí wọn ń gbé. Kí ẹni tí ó jẹ lówó gba gbogbo ohun ìní rẹ̀, kí ẹni ẹlẹ́ni sì kó èrè iṣẹ́ rẹ̀. Kí ó má bá aláàánú pàdé, kí ẹnikẹ́ni má sì ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n ti di aláìníbaba. Kí ìran rẹ̀ run, kí orúkọ rẹ̀ parẹ́ lórí àwọn ọmọ rẹ̀. Kí OLUWA máa ranti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba rẹ̀, kí ó má sì pa ẹ̀ṣẹ̀ ìyá rẹ̀ rẹ́. Kí OLUWA máa ranti ẹ̀ṣẹ̀ wọn nígbà gbogbo, kí á má sì ranti ìran wọn mọ́ láyé. Nítorí pé kò ronú láti ṣàánú, ṣugbọn ó ṣe inúnibíni talaka ati aláìní, ati sí oníròbìnújẹ́ títí a fi pa wọ́n. Ó fẹ́ràn láti máa ṣépè; nítorí náà kí èpè rẹ̀ dà lé e lórí; inú rẹ̀ kò dùn sí ìre, nítorí náà kí ìre jìnnà sí i. Ó gbé èpè wọ̀ bí ẹ̀wù, kí èpè mù ún bí omi, kí ó sì wọ inú egungun rẹ̀ dé mùdùnmúdùn. Kí èpè di aṣọ ìbora fún un, ati ọ̀já ìgbànú. Bẹ́ẹ̀ ni kí OLUWA ṣe sí àwọn ọ̀tá mi, àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ibi nípa mi! Ṣugbọn, ìwọ OLUWA Ọlọrun mi, gbèjà mi nítorí orúkọ rẹ, gbà mí! Nítorí ìfẹ́ rere rẹ tí kì í yẹ̀. Nítorí pé talaka ati aláìní ni mí, ọkàn mí bàjẹ́ lọpọlọpọ. Mò ń parẹ́ lọ bí òjìji àṣáálẹ́, a ti gbọ̀n mí dànù bí eṣú. Ẹsẹ̀ mi kò ranlẹ̀ mọ́ nítorí ààwẹ̀ gbígbà, mo rù kan egungun. Mo di ẹni ẹ̀gàn níwájú àwọn ọ̀tá mi, wọ́n ń wò mí ní àwòmirí. Ràn mí lọ́wọ́, OLUWA, Ọlọrun mi, gbà mí, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀. Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ni èyí, kí wọn mọ̀ pé, ìwọ OLUWA ni o ṣe é. Kí wọn máa ṣépè, ṣugbọn kí ìwọ máa súre. Kí ojú ti àwọn alátakò mi, kí inú èmi, iranṣẹ rẹ, sì máa dùn. Kí ìtìjú bo àwọn ọ̀tá mi bi aṣọ, àní, kí wọn gbé ìtìjú wọ̀ bí ẹ̀wù. N óo máa fi ẹnu mi yin OLUWA gidigidi, àní, n óo máa yìn ín ní àwùjọ ọ̀pọ̀ eniyan. Nítorí pé ó dúró ti aláìní láti gbà á lọ́wọ́ àwọn tí ó dájọ́ ikú fún un. OLUWA wí fún oluwa mi, ọba, pé, “Jókòó sí apá ọ̀tún mi, títí tí n óo fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.” OLUWA yóo na ọ̀pá àṣẹ rẹ tí ó lágbára láti Sioni. O óo jọba láàrin àwọn ọ̀tá rẹ. Àwọn eniyan rẹ yóo fi tọkàntọkàn fa ara wọn kalẹ̀, lọ́jọ́ tí o bá ń kó àwọn ọmọ ogun rẹ jọ lórí òkè mímọ́. Àwọn ọ̀dọ́ yóo jáde tọ̀ ọ́ wá bí ìrì òwúrọ̀. OLUWA ti búra, kò sì ní yí ọkàn rẹ̀ pada, pé, “Alufaa ni ọ́ títí lae, nípasẹ̀ Mẹlikisẹdẹki.” OLUWA wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ, yóo rún àwọn ọba wómúwómú ní ọjọ́ ibinu rẹ̀. Yóo ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè, ọpọlọpọ òkú ni yóo sì sùn ninu wọn; yóo sì run àwọn ìjòyè káàkiri ilẹ̀ ayé. Ọba yóo mu omi ninu odò ẹ̀bá ọ̀nà, nítorí náà yóo sì gbé orí rẹ̀ sókè bí aṣẹ́gun. Ẹ yin OLUWA! N óo dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA tọkàntọkàn, láàrin àwọn olódodo, ati ní àwùjọ àwọn eniyan. Iṣẹ́ OLUWA tóbi, àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ sí i sì ń wá a kiri. Iṣẹ́ rẹ̀ lọ́lá, ó sì lógo, òdodo rẹ̀ sì wà títí lae. OLUWA mú kí á máa ranti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, olóore ọ̀fẹ́ ni OLUWA, àánú rẹ̀ sì pọ̀. A máa pèsè oúnjẹ fún àwọn tí wọn bẹ̀rù rẹ̀, a sì máa ranti majẹmu rẹ̀ títí lae. Ó ti fi agbára iṣẹ́ rẹ̀ han àwọn eniyan rẹ̀, nípa fífún wọn ní ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ tọ́, ó sì tọ̀nà, gbogbo ìlànà rẹ̀ sì dájú. Wọ́n wà títí lae ati laelae, ní òtítọ́ ati ìdúróṣinṣin. Ó ṣètò ìràpadà fún àwọn eniyan rẹ̀, ó fi ìdí majẹmu rẹ̀ múlẹ̀ títí lae, mímọ́ ni orúkọ rẹ̀, ó sì lọ́wọ̀. Ìbẹ̀rù OLUWA ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n, gbogbo àwọn tí ó bá ń tẹ̀lé ìlànà rẹ̀, á máa ní ìmọ̀ pípé. Títí lae ni ìyìn rẹ̀. Ẹ yin OLUWA! Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bẹ̀rù OLUWA, tí inú rẹ̀ sì dùn lọpọlọpọ sí òfin rẹ̀. Àwọn arọmọdọmọ rẹ̀ yóo jẹ́ alágbára láyé, a óo sì bukun ìran ẹni tí ó dúró ṣinṣin. Ọlá ati ọlà yóo wà ní ilé rẹ̀, Òdodo rẹ̀ wà títí lae. Ìmọ́lẹ̀ yóo tàn fún olódodo ninu òkùnkùn, olóore ọ̀fẹ́ ni OLUWA, aláàánú ni, a sì máa ṣòdodo. Yóo máa dára fún ẹni tí ó bá lójú àánú, tí ó sì ń yáni ní nǹkan, tí ó ń ṣe ẹ̀tọ́ ní gbogbo ọ̀nà. A kò ní ṣí olódodo ní ipò pada lae, títí ayé ni a óo sì máa ranti rẹ̀. Ìròyìn ibi kì í bà á lẹ́rù, ọkàn rẹ̀ dúró ṣinṣin, ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA. Ọkàn rẹ̀ a máa balẹ̀, ẹ̀rù kì í bà á, níkẹyìn, èrò rẹ̀ a sì máa ṣẹ lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ó lawọ́, á máa ṣoore fún àwọn talaka, òdodo rẹ̀ wà títí lae, yóo di alágbára, a óo sì dá a lọ́lá. Ìbànújẹ́ yóo bá eniyan burúkú nígbà tí ó bá rí i. Yóo pa eyín keke, yóo pòórá, ìfẹ́ rẹ̀ yóo sì di asán. Ẹ yin OLUWA! Ẹ yìn ín, ẹ̀yin iranṣẹ OLUWA. Ẹ yin orúkọ OLUWA. Kí á yin orúkọ OLUWA, láti ìsinsìnyìí lọ títí laelae. Láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn, kí á máa yin orúkọ OLUWA. OLUWA ju gbogbo orílẹ̀-èdè lọ, ògo rẹ̀ sì ga ju ọ̀run lọ. Ta ló dàbí OLUWA Ọlọrun wa, tí ó gúnwà sí òkè ọ̀run, ẹni tí ó bojú wo ilẹ̀ láti wo ọ̀run ati ayé? Ó gbé talaka dìde láti inú erùpẹ̀, ó sì gbé aláìní sókè láti orí eérú, láti mú wọn jókòó láàrin àwọn ìjòyè, àní, àwọn ìjòyè àwọn eniyan rẹ̀. Ó sọ àgàn di ọlọ́mọ, ó sọ ọ́ di abiyamọ onínúdídùn. Ẹ máa yin OLUWA. Nígbà tí Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, tí àwọn ọmọ Jakọbu jáde kúrò láàrin àwọn tí ń sọ èdè àjèjì, Juda di ilé mímọ́ rẹ̀, Israẹli sì di ìjọba rẹ̀. Òkun rí i, ó sá, Jọdani rí i, ó pada sẹ́yìn. Àwọn òkè ńláńlá ń fò bí àgbò, àwọn òkè kéékèèké ń fò bí ọmọ aguntan. Kí ló dé, tí o fi sá, ìwọ òkun? Kí ló ṣẹlẹ̀ tí o fi pada sẹ́yìn, ìwọ Jọdani? Ẹ̀yin òkè ńlá, kí ló dé tí ẹ fi fò bí àgbò? Ẹ̀yin òkè kéékèèké, kí ló ṣẹlẹ̀ tí ẹ fi fò bí ọmọ aguntan? Wárìrì níwájú OLUWA, ìwọ ilẹ̀, wárìrì níwájú Ọlọrun Jakọbu. Ẹni tí ó sọ àpáta di adágún omi, tí ó sì sọ akọ òkúta di orísun omi. Ògo kì í ṣe fún wa, OLUWA, Kì í ṣe fún wa, orúkọ rẹ nìkan ṣoṣo ni kí á yìn lógo, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, ati nítorí òtítọ́ rẹ. Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè yóo fi bèèrè pé, níbo ni Ọlọrun wa wà? Ọlọrun wa wà ní ọ̀run, ó ń ṣe ohun tí ó wù ú. Fadaka ati wúrà ni ère tiwọn, iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni wọ́n. Wọ́n ní ẹnu, ṣugbọn wọn kò lè sọ̀rọ̀, wọ́n lójú, ṣugbọn wọn kò ríran. Wọ́n létí, ṣugbọn wọn kò gbọ́ràn, wọ́n nímú, ṣugbọn wọn kò gbóòórùn. Wọ́n lọ́wọ́, ṣugbọn wọn kò lè lò ó, wọ́n lẹ́sẹ̀, ṣugbọn wọn kò lè rìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè gbin. Àwọn tí ó ń yá àwọn ère náà dàbí wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé wọn. Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, òun ni olùrànlọ́wọ́ ati aláàbò yín. Ẹ̀yin ìdílé Aaroni, ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, òun ni olùrànlọ́wọ́ ati aláàbò yín. Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ gbẹ́kẹ̀lé e, òun ni olùrànlọ́wọ́ ati aláàbò yín. OLUWA ranti wa, yóo bukun wa, yóo bukun ilé Israẹli, yóo bukun ìdílé Aaroni. Yóo bukun àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, ati àwọn ọlọ́lá ati àwọn mẹ̀kúnnù. OLUWA yóo jẹ́ kí ẹ máa bí sí i, àtẹ̀yin àtàwọn ọmọ yín. Kí OLUWA tí ó dá ọ̀run ati ayé bukun yín! OLUWA ló ni ọ̀run, ṣugbọn ó fi ayé fún àwọn eniyan. Àwọn òkú kò lè yin OLUWA, àní àwọn tí wọ́n ti dákẹ́ ninu ibojì. Ṣugbọn àwa yóo máa yin OLUWA, láti ìsinsìnyìí lọ, ati títí laelae. Ẹ máa yin OLUWA. Mo fẹ́ràn OLUWA nítorí pé ó gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ mi. Nítorí pé ó tẹ́tí sí mi, nítorí náà, n óo máa ké pè é níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè. Tàkúté ikú yí mi ká; ìrora isà òkú dé bá mi; ìyọnu ati ìnira sì bò mí mọ́lẹ̀. Nígbà náà ni mo ké pe OLUWA, mo ní, “OLUWA, mo bẹ̀ ọ́, gbà mí!” Olóore ọ̀fẹ́ ati olódodo ni OLUWA, aláàánú ni Ọlọrun wa. OLUWA a máa pa àwọn onírẹ̀lẹ̀ mọ́; nígbà tí a rẹ̀ mí sílẹ̀, ó gbà mí. Sinmi ìwọ ọkàn mi, bíi ti àtẹ̀yìnwá, nítorí pé OLUWA ṣeun fún ọ lọpọlọpọ. Nítorí ìwọ OLUWA ti gba ọkàn mi lọ́wọ́ ikú, o gba ojú mi lọ́wọ́ omijé, o sì gba ẹsẹ̀ mi lọ́wọ́ ìṣubú. Mò ń rìn níwájú OLUWA, lórí ilẹ̀ alààyè. Igbagbọ mi kò yẹ̀, nígbà tí mo tilẹ̀ wí pé, “Ìpọ́njú dé bá mi gidigidi.” Mo wí ninu ìdààmú ọkàn pé, “Èké ni gbogbo eniyan.” Kí ni n óo san fún OLUWA, nítorí gbogbo oore rẹ̀ lórí mi? N óo mu ẹbọ nǹkan mímu wá fún OLUWA, n óo sì pe orúkọ rẹ̀. N óo san ẹ̀jẹ́ mi fún OLUWA, lójú gbogbo àwọn eniyan rẹ̀. Iyebíye ni ikú àwọn eniyan rẹ̀ mímọ́ lójú OLUWA. OLUWA, iranṣẹ rẹ ni mo jẹ́, iranṣẹ rẹ ni mo jẹ́, àní, ọmọ iranṣẹbinrin rẹ. O ti tú ìdè mi. N óo rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ, n óo sì pe orúkọ rẹ OLUWA. N óo san ẹ̀jẹ́ mi fún OLUWA lójú gbogbo àwọn eniyan rẹ̀, ninu àgbàlá ilé OLUWA, láàrin rẹ, ìwọ ìlú Jerusalẹmu. Ẹ máa yin OLUWA! Ẹ máa yin OLUWA, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè! Ẹ yìn ín gbogbo ẹ̀yin eniyan, Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ tóbi sí wa, òtítọ́ rẹ̀ sì wà títí laelae. Ẹ máa yin OLUWA. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Jẹ́ kí Israẹli wí pé, “Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.” Kí àwọn ará ilé Aaroni wí pé, “Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.” Kí àwọn tí ó bẹ̀rù OLUWA wí pé, “Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.” Ninu ìpọ́njú, mo ké pe OLUWA, ó dá mi lóhùn, ó sì tú mi sílẹ̀. Nígbà tí OLUWA wà pẹlu mi, ẹ̀rù kò bà mí. Kí ni eniyan lè fi mí ṣe? OLUWA wà pẹlu mi láti ràn mí lọ́wọ́, nítorí náà, n óo wo àwọn tí wọ́n kórìíra mi pẹlu ayọ̀ ìṣẹ́gun. Ó sàn láti sá di OLUWA, ju ati gbẹ́kẹ̀lé eniyan lọ. Ó sàn láti sá di OLUWA, ju ati gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìjòyè. Gbogbo orílẹ̀-èdè dòòyì ká mi, ṣugbọn ní orúkọ OLUWA, mo pa wọ́n run! Wọ́n yí mi ká, àní, wọ́n dòòyì ká mi, ṣugbọn ni orúkọ OLUWA, mo pa wọ́n run! Wọ́n ṣùrù bò mí bí oyin, ṣugbọn kíá ni wọ́n kú bí iná ìṣẹ́pẹ́; ní orúkọ OLUWA, mo pa wọ́n run. Wọ́n gbógun tì mí gidigidi, tóbẹ́ẹ̀ tí mo fẹ́rẹ̀ ṣubú, ṣugbọn OLUWA ràn mí lọ́wọ́. OLUWA ni agbára ati orin mi, ó ti di olùgbàlà mi. Ẹ gbọ́ orin ayọ̀ ìṣẹ́gun, ninu àgọ́ àwọn olódodo. “Ọwọ́ ọ̀tún OLUWA ti ṣe iṣẹ́ agbára ńlá. A gbé ọwọ́ ọ̀tún OLUWA ga, ọwọ́ ọ̀tún OLUWA ti ṣe iṣẹ́ agbára ńlá!” N ò ní kú, yíyè ni n óo yè, n óo sì máa fọnrere nǹkan tí OLUWA ṣe. OLUWA jẹ mí níyà pupọ, ṣugbọn kò fi mí lé ikú lọ́wọ́. Ṣí ìlẹ̀kùn òdodo fún mi, kí n lè gba ibẹ̀ wọlé, kí n sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA. Èyí ni ẹnu ọ̀nà OLUWA; àwọn olódodo yóo gba ibẹ̀ wọlé. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, nítorí pé o gbọ́ ohùn mi, o sì ti di olùgbàlà mi. Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀, ni ó di pataki igun ilé. OLUWA ló ṣe èyí; ó sì jẹ́ ohun ìyanu lójú wa. Òní ni ọjọ́ tí OLUWA dá, ẹ jẹ́ kí á máa yọ̀, kí inú wa sì máa dùn. OLUWA, à ń bẹ̀ ọ́, gbà wá, OLUWA, à ń bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí á ṣe àṣeyege. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ OLUWA, láti inú ilé rẹ ni a ti ń yìn ọ́, OLUWA. OLUWA ni Ọlọrun, ó sì ti tan ìmọ́lẹ̀ sí wa. Pẹlu ẹ̀ka igi lọ́wọ́, ẹ bẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ ìwọ́de ẹbọ náà, títí dé ibi ìwo pẹpẹ. Ìwọ ni Ọlọrun mi, n óo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ. Ìwọ ni Ọlọrun mi, n óo máa gbé ọ ga. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ìgbé ayé wọn kò lábàwọ́n, àní àwọn tí ń rìn gẹ́gẹ́ bí òfin OLUWA. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́, tí wọn ń fi tọkàntọkàn ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Àwọn tí wọn kò dẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn tí wọn ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀. O ti pàṣẹ pé kí á fi tọkàntọkàn pa òfin rẹ mọ́, Ìbá ti dára tó tí mo bá lè dúró ṣinṣin ninu ìlànà rẹ! Òun ni ojú kò fi ní tì mí, nítorí pé òfin rẹ ni mò ń tẹ̀lé. N óo yìn ọ́ pẹlu inú mímọ́, bí mo ṣe ń kọ́ ìlànà òdodo rẹ. N óo máa pa òfin rẹ mọ́, má kọ̀ mí sílẹ̀ patapata. Báwo ni ọdọmọkunrin ṣe lè mú kí ọ̀nà rẹ̀ mọ́? Nípa títẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ ni. Tọkàntọkàn ni mo fi ń ṣe ìfẹ́ rẹ, má jẹ́ kí n ṣìnà kúrò ninu òfin rẹ. Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ sọ́kàn, kí n má baà ṣẹ̀ ọ́. Ìyìn ni fún ọ, OLUWA, kọ́ mi ní ìlànà rẹ! Mo fi ẹnu mi kéde gbogbo àṣẹ tí o pa. Mo láyọ̀ ninu pípa òfin rẹ mọ́, bí ẹni tí ó ní ọpọlọpọ ọrọ̀. N óo máa ṣe àṣàrò ninu òfin rẹ, n óo sì kọjú sí ọ̀nà rẹ. N óo láyọ̀ ninu àwọn ìlànà rẹ, n kò ní gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ. Ṣe ọpọlọpọ oore fún èmi iranṣẹ rẹ, kí n lè wà láàyè, kí n sì máa tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ. Là mí lójú, kí n lè rí àwọn nǹkan ìyanu tí ó wà ninu òfin rẹ. Àlejò ni mí láyé, má fi òfin rẹ pamọ́ fún mi. Òùngbẹ títẹ̀lé òfin rẹ ń gbẹ ọkàn mi, nígbà gbogbo. O bá àwọn onigbeeraga wí, àwọn ẹni ègún, tí wọn kò pa òfin rẹ mọ́. Mú ẹ̀gàn ati àbùkù wọn kúrò lára mi, nítorí pé mo ti pa òfin rẹ mọ́. Bí àwọn ìjòyè tilẹ̀ gbìmọ̀ràn ọ̀tẹ̀ nítorí mi, sibẹ, èmi iranṣẹ rẹ yóo ṣe àṣàrò lórí ìlànà rẹ. Àwọn òfin rẹ ni dídùn inú mi, àwọn ni olùdámọ̀ràn mi. Mo di ẹni ilẹ̀, sọ mí di alààyè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ. Nígbà tí mo jẹ́wọ́ gbogbo ìṣe mi, o dá mi lóhùn; kọ́ mi ní ìlànà rẹ. La òfin rẹ yé mi, n óo sì máa ṣe àṣàrò lórí iṣẹ́ ìyanu rẹ. Ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn mi nítorí ìbànújẹ́, mú mi lọ́kàn le gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ. Mú ìwà èké jìnnà sí mi, kí o sì fi oore ọ̀fẹ́ kọ́ mi ní òfin rẹ. Mo ti yan ọ̀nà òtítọ́, mo ti fi ọkàn sí òfin rẹ. Mo pa òfin rẹ mọ́, OLUWA, má jẹ́ kí ojú ó tì mí. N óo yára láti pa òfin rẹ mọ́, nígbà tí o bá mú òye mi jinlẹ̀ sí i. OLUWA, kọ́ mi ní ìlànà rẹ, n óo sì pa wọ́n mọ́ dé òpin. Là mí lóye, kí n lè máa pa òfin rẹ mọ́, kí n sì máa fi tọkàntọkàn pa wọ́n mọ́. Tọ́ mi sí ọ̀nà nípa òfin rẹ, nítorí pé mo láyọ̀ ninu rẹ̀. Mú kí ọkàn mi fà sí òfin rẹ, kí ó má fà sí ọrọ̀ ayé. Yí ojú mi kúrò ninu wíwo nǹkan asán, sọ mí di alààyè ní ọ̀nà rẹ. Mú ìlérí rẹ ṣẹ fún iranṣẹ rẹ, àní, ìlérí tí o ṣe fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ. Mú ẹ̀gàn tí ń bà mí lẹ́rù kúrò, nítorí pé ìlànà rẹ dára. Wò ó, ọkàn mi fà sí ati máa tẹ̀lé ìlànà rẹ, sọ mí di alààyè nítorí òdodo rẹ! Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn mí, OLÚWA, kí o sì gbà mí là gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Nígbà náà ni n óo lè dá àwọn tí ń gàn mí lóhùn, nítorí mo gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ. Má gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ rẹ lẹ́nu mi rárá, nítorí ìrètí mi ń bẹ ninu ìlànà rẹ. N óo máa pa òfin rẹ mọ́ nígbà gbogbo, lae ati laelae. N óo máa rìn fàlàlà, nítorí pé mo tẹ̀lé ìlànà rẹ. N óo máa sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba, ojú kò sì ní tì mí. Mo láyọ̀ ninu òfin rẹ, nítorí tí mo fẹ́ràn rẹ̀. Mo bọ̀wọ̀ fún àṣẹ rẹ tí mo fẹ́ràn, n óo sì máa ṣe àṣàrò lórí ìlànà rẹ. Ranti ọ̀rọ̀ tí o bá èmi iranṣẹ rẹ sọ, èyí tí ó fún mi ní ìrètí. Ohun tí ó ń tù mí ninu ní àkókò ìpọ́njú ni pé: ìlérí rẹ mú mi wà láàyè. Àwọn onigbeeraga ń kẹ́gàn mi gidigidi, ṣugbọn n ò kọ òfin rẹ sílẹ̀. Mo ranti òfin rẹ àtijọ́, OLUWA, ọkàn mi sì balẹ̀. Inú mi á máa ru, nígbà tí mo bá rí àwọn eniyan burúkú, tí wọn ń rú òfin rẹ. Òfin rẹ ni mò ń fi ń ṣe orin kọ, lákòókò ìrìn àjò mi láyé. Mo ranti orúkọ rẹ lóru; OLUWA, mo sì pa òfin rẹ mọ́: Èyí ni ìṣe mi: Èmi a máa pa òfin rẹ mọ́. OLUWA, ìwọ nìkan ni mo ní; mo ṣe ìlérí láti pa òfin rẹ mọ́. Tọkàntọkàn ni mò ń wá ojurere rẹ, ṣe mí lóore gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Nígbà tí mo ronú nípa ìṣe mi, mo yipada sí ìlànà rẹ; mo yára, bẹ́ẹ̀ ni n kò lọ́ra láti pa òfin rẹ mọ́. Bí okùn àwọn eniyan burúkú tilẹ̀ wé mọ́ mi, n kò ní gbàgbé òfin rẹ. Mo dìde lọ́gànjọ́ láti yìn ọ́, nítorí ìlànà òdodo rẹ. Ọ̀rẹ́ gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ ni mí, àní, àwọn tí wọn ń pa òfin rẹ mọ́. OLUWA, ayé kún fún ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀; kọ́ mi ní ìlànà rẹ. OLUWA, o ti ṣeun fún èmi iranṣẹ rẹ, gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Fún mi ní òye ati ìmọ̀ pípé, nítorí mo ní igbagbọ ninu àṣẹ rẹ. Kí o tó jẹ mí níyà, mo yapa kúrò ninu òfin rẹ; ṣugbọn nisinsinyii, mò ń mú àṣẹ rẹ ṣẹ. OLUWA rere ni ọ́, rere ni o sì ń ṣe; kọ́ mi ní ìlànà rẹ. Àwọn onigbeeraga ti wé irọ́ mọ́ mi lẹ́sẹ̀, ṣugbọn èmi fi tọkàntọkàn pa òfin rẹ mọ́. Ọkàn wọn ti yigbì, ṣugbọn èmi láyọ̀ ninu òfin rẹ. Ìpọ́njú tí mo rí ṣe mí ní anfaani, ó mú kí n kọ́ nípa ìlànà rẹ. Òfin rẹ níye lórí fún mi, ó ju ẹgbẹẹgbẹrun wúrà ati fadaka lọ. Ìwọ ni o mọ mí, ìwọ ni o dá mi, fún mi ní òye kí n lè kọ́ òfin rẹ. Inú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ yóo máa dùn nígbà tí wọ́n bá rí mi, nítorí pé mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ. OLUWA, mo mọ̀ pé ìdájọ́ rẹ tọ̀nà, ati pé lórí ẹ̀tọ́ ni o pọ́n mi lójú. Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ máa tù mí ninu, gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí o ṣe fún èmi, iranṣẹ rẹ. Ṣàánú mi, kí n lè wà láàyè, nítorí pé òfin rẹ ni ìdùnnú mi. Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn onigbeeraga, nítorí wọ́n ṣe àrékérekè sí mi láìnídìí; ní tèmi, n óo máa ṣe àṣàrò lórí òfin rẹ. Jẹ́ kí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ tọ̀ mí wá, kí wọ́n lè mọ òfin rẹ. Níti pípa òfin rẹ mọ́, jẹ́ kí n pé, kí ojú má baà tì mí. Mo wá ìgbàlà rẹ títí, àárẹ̀ mú ọkàn mi; ṣugbọn mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ. Mo fojú sọ́nà títí, agara dá mi, níbi tí mo tí ń retí ìmúṣẹ ìlérí rẹ. Mo ní, “Nígbà wo ni o óo tù mí ninu?” Mo dàbí agbè ọtí tí ó ti di àlòpatì, sibẹ, n kò gbàgbé ìlànà rẹ. Èmi iranṣẹ rẹ yóo ti dúró pẹ́ tó? Nígbà wo ni ìwọ óo dájọ́ fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi? Àwọn onigbeeraga ti gbẹ́ kòtò sílẹ̀ dè mí, àní, àwọn tí kì í pa òfin rẹ mọ́. Gbogbo òfin rẹ ló dájú; ràn mí lọ́wọ́, nítorí wọ́n ń fi ìwà èké ṣe inúnibíni mi. Wọ́n fẹ́rẹ̀ pa mí run láyé, ṣugbọn n kò kọ ìlànà rẹ sílẹ̀. Dá ẹ̀mí mi sí gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, kí n lè máa mú gbogbo àṣẹ rẹ ṣẹ. OLUWA, títí lae ni ọ̀rọ̀ rẹ fìdí múlẹ̀ lọ́run. Òtítọ́ rẹ wà láti ìrandíran; o ti fi ìdí ayé múlẹ̀, ó sì dúró. Ohun gbogbo wà gẹ́gẹ́ bí ìlànà rẹ, títí di òní, nítorí pé iranṣẹ rẹ ni gbogbo wọn. Bí kò bá jẹ́ pé òfin rẹ jẹ́ ìdùnnú mi, ǹ bá ti ṣègbé ninu ìpọ́njú. Lae, n kò ní gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ, nítorí pé, nípasẹ̀ wọn ni o fi mú mi wà láyé. Ìwọ ni o ni mí, gbà mí; nítorí pé mo ti kọ́ ẹ̀kọ́ rẹ. Àwọn eniyan burúkú ba dè mí, wọ́n fẹ́ pa mí run, ṣugbọn mò ń ṣe àṣàrò lórí òfin rẹ. Mo ti rí i pé kò sí ohun tí ó lè pé tán, àfi òfin rẹ nìkan ni kò lópin. Mo fẹ́ràn òfin rẹ lọpọlọpọ! Òun ni mo fi ń ṣe àṣàrò tọ̀sán-tòru. Ìlànà rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ, nítorí pé òun ni ó ń darí mi nígbà gbogbo. Òye mi ju ti àwọn olùkọ́ mi lọ, nítorí pé ìlànà rẹ ni mo fi ń ṣe àṣàrò. Òye mi ju ti àwọn àgbà lọ, nítorí pé mo gba ẹ̀kọ́ rẹ. N kò rin ọ̀nà ibi kankan, kí n lè pa òfin rẹ mọ́. N kò yapa kúrò ninu òfin rẹ, nítorí pé o ti kọ́ mi. Ọ̀rọ̀ rẹ dùn mọ́ mi pupọ, ó dùn ju oyin lọ. Nípa ẹ̀kọ́ rẹ ni mo fi ní òye, nítorí náà mo kórìíra gbogbo ìwà èké. Ọ̀rọ̀ rẹ ni àtùpà fún ẹsẹ̀ mi, òun ni ìmọ́lẹ̀ sí ọ̀nà mi. Mo ti búra, n óo sì mú un ṣẹ, pé n óo máa pa òfin òdodo rẹ mọ́. Ojú ń pọ́n mi lọpọlọpọ, sọ mí di alààyè, OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Gba ẹbọ ìyìn àtọkànwá mi, OLUWA, kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ. Ayé mi wà ninu ewu nígbà gbogbo, ṣugbọn n kò gbàgbé òfin rẹ. Àwọn eniyan burúkú ti dẹ okùn sílẹ̀ dè mí, ṣugbọn n kò kọ ìlànà rẹ sílẹ̀. Ìlànà rẹ ni ogún mi títí lae, nítorí pé òun ni ayọ̀ mi. Mo ti pinnu láti máa tẹ̀lé ìlànà rẹ nígbà gbogbo, àní, títí dé òpin. Mo kórìíra àwọn oníyèméjì, ṣugbọn mo fẹ́ràn òfin rẹ. Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi ati asà mi, mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ. Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin aṣebi, kí n lè pa òfin Ọlọrun mi mọ́. Gbé mi ró gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ, kí n lè wà láàyè, má sì dójú ìrètí mi tì mí. Gbé mi ró, kí n lè wà láìléwu, kí n lè máa ka ìlànà rẹ sí nígbà gbogbo. O ti kọ gbogbo àwọn tí ó yapa kúrò ninu ìlànà rẹ sílẹ̀, nítorí pé asán ni gbogbo ẹ̀tàn wọn. O ti pa àwọn eniyan burúkú tì, bí ìdàrọ́ irin, nítorí náà ni mo ṣe fẹ́ràn ìlànà rẹ. Mo wárìrì nítorí pé mo bẹ̀rù rẹ, mo sì bẹ̀rù ìdájọ́ rẹ. Mo ti ṣe ohun tí ó tọ́ tí ó sì yẹ, má fi mí sílẹ̀ fún àwọn tí wọn ń ni mí lára. Ṣe ìlérí ìrànlọ́wọ́ fún ire èmi iranṣẹ rẹ, má sì jẹ́ kí àwọn onigbeeraga ni mí lára. Mo fojú sọ́nà títí, agara dá mi, níbi tí mo tí ń retí ìgbàlà rẹ, ati ìmúṣẹ ìlérí òdodo rẹ. Ṣe sí èmi iranṣẹ rẹ, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ. Iranṣẹ rẹ ni mí, fún mi lóye, kí n lè mọ ìlànà rẹ. OLUWA, ó tó àkókò fún ọ láti ṣe nǹkankan, nítorí àwọn eniyan ń rú òfin rẹ. Nítorí náà ni èmi ṣe fẹ́ràn òfin rẹ ju wúrà lọ; àní, ju ojúlówó wúrà. Nítorí náà, èmi ń tẹ̀lé gbogbo ẹ̀kọ́ rẹ, mo sì kórìíra gbogbo ọ̀nà èké. Òfin rẹ dára, nítorí náà ni mo ṣe ń pa wọ́n mọ́. Ìṣípayá ọ̀rọ̀ rẹ a máa fúnni ní ìmọ́lẹ̀, a sì máa fi òye fún àwọn onírẹ̀lẹ̀. Mo la ẹnu, mò ń mí hẹlẹ, nítorí pé mò ń lépa òfin rẹ. Kọjú sí mi kí o ṣe mí lóore bí o ti máa ń ṣe sí àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ. Mú ẹsẹ̀ mi dúró gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ, má sì jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ kankan jọba lórí mi. Gbà mí lọ́wọ́ ìnilára àwọn eniyan, kí n lè máa tẹ̀lé ìlànà rẹ. Jẹ́ kí ojú rẹ mọ́lẹ̀ sí ara èmi iranṣẹ rẹ; kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ. Omijé ń dà lójú mi pòròpòrò, nítorí pé àwọn eniyan kò pa òfin rẹ mọ́. Olódodo ni ọ́, OLUWA, ìdájọ́ rẹ sì tọ́. Òdodo ni o fi pa àṣẹ rẹ, òtítọ́ patapata ni. Mò ń tara gidigidi, nítorí pé àwọn ọ̀tá mi gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ. A ti yẹ ọ̀rọ̀ rẹ wò fínnífínní, ó dúró ṣinṣin, mo sì fẹ́ràn rẹ̀. Bí mo tilẹ̀ kéré, tí ayé sì kẹ́gàn mi, sibẹ n kò gbàgbé ìlànà rẹ. Òdodo rẹ wà títí lae, òtítọ́ sì ni òfin rẹ. Ìyọnu ati ìpayà dé bá mi, ṣugbọn mo láyọ̀ ninu òfin rẹ. Òdodo ni ìlànà rẹ títí lae, fún mi ní òye kí n lè wà láàyè. Tọkàntọkàn ni mo fi ń ké pè ọ́, OLUWA, dá mi lóhùn; n óo sì máa tẹ̀lé ìlànà rẹ. Mo ké pè ọ́; gbà mí, n óo sì máa mú àṣẹ rẹ ṣẹ. Mo jí ní òwúrọ̀ kutukutu, mo sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́; mò ń retí ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ rẹ. N kò fi ojú ba oorun ní gbogbo òru, kí n lè máa ṣe àṣàrò lórí ọ̀rọ̀ rẹ. Gbóhùn mi nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, OLÚWA, dá mi sí nítorí òtítọ́ rẹ. Àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi súnmọ́ tòsí; wọ́n jìnnà sí òfin rẹ. Ṣugbọn ìwọ wà nítòsí, OLUWA, òtítọ́ sì ni gbogbo òfin rẹ. Ó pẹ́ tí mo ti kọ́ ninu ìlànà rẹ, pé o ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí lae. Wo ìpọ́njú mi, kí o gbà mí, nítorí n kò gbàgbé òfin rẹ. Gba ẹjọ́ mi rò, kí o sì gbà mí, sọ mí di alààyè gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Ìgbàlà jìnnà sí àwọn eniyan burúkú, nítorí wọn kò wá ìlànà rẹ. Àánú rẹ pọ̀, OLUWA, sọ mí di alààyè gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ rẹ. Àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi ati àwọn ọ̀tá mi pọ̀, ṣugbọn n kò yapa kúrò ninu ìlànà rẹ. Mò ń wo àwọn ọ̀dàlẹ̀ pẹlu ìríra, nítorí wọn kì í pa òfin rẹ mọ́. Wo bí mo ti fẹ́ ẹ̀kọ́ rẹ tó! Dá mi sí gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀. Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ, gbogbo òfin òdodo rẹ ni yóo máa wà títí lae. Àwọn ìjòyè ń ṣe inúnibíni mi láìnídìí, ṣugbọn mo bẹ̀rù ọ̀rọ̀ rẹ tọkàntọkàn. Mo láyọ̀ ninu ọ̀rọ̀ rẹ, bí ẹni pé mo ní ọpọlọpọ ìkógun. Mo kórìíra èké ṣíṣe, ara mi kọ̀ ọ́, ṣugbọn mo fẹ́ràn òfin rẹ. Nígbà meje lojoojumọ ni mò ń yìn ọ́ nítorí òfin òdodo rẹ. Alaafia ńláńlá ń bẹ fún àwọn tí ó fẹ́ràn òfin rẹ, kò sí ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀. Mò ń retí ìgbàlà rẹ, OLUWA, mo sì ń pa àwọn òfin rẹ mọ́. Mò ń pa àṣẹ rẹ mọ́, mo fẹ́ràn wọn gidigidi. Mo gba ẹ̀kọ́ rẹ, mo sì ń tẹ̀lé ìlànà rẹ; gbogbo ìṣe mi ni ò ń rí. Jẹ́ kí igbe mi dé ọ̀dọ̀ rẹ, OLUWA, fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi dé iwájú rẹ, kí o sì gbà mí là gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Ẹnu mi yóo kún fún ìyìn rẹ, pé o ti kọ́ mi ní ìlànà rẹ. N óo máa fi ọ̀rọ̀ rẹ ṣe orin kọ, nítorí pé gbogbo òfin rẹ ni ó tọ̀nà. Múra láti ràn mí lọ́wọ́, nítorí pé mo ti gba ẹ̀kọ́ rẹ. Ọkàn mi ń fà sí ìgbàlà rẹ, OLUWA; òfin rẹ sì ni inú dídùn mi. Dá mi sí kí n lè máa yìn ọ́, sì jẹ́ kí òfin rẹ ràn mí lọ́wọ́. Mo ti ṣìnà bí aguntan tó sọnù; wá èmi, iranṣẹ rẹ, rí, nítorí pé n kò gbàgbé òfin rẹ. OLUWA ni mo ké pè, nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú, ó sì dá mi lóhùn. OLUWA, gbà mí lọ́wọ́ àwọn èké, ati lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́tàn. Kí ni a óo fi san án fun yín? Kí ni a óo sì ṣe si yín, ẹ̀yin ẹlẹ́tàn? Ọfà mímú ni a óo ta yín, a óo sì dáná sun yín. Mo gbé! Nítorí pé mo dàbí àlejò tó wọ̀ ní Meṣeki, tí ń gbé ààrin àwọn àgọ́ Kedari. Ó pẹ́ jù tí mo tí ń bá àwọn tí ó kórìíra alaafia gbé. Alaafia ni èmi fẹ́, ṣugbọn nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, ìjà ṣá ni tiwọn. Mo gbójú sókè wo àwọn òkè, níbo ni ìrànlọ́wọ́ mi ti ń wá? Ìrànlọ́wọ́ mi ń ti ọ̀dọ̀ OLUWA wá, ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé. Kò ní jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ ó yẹ̀, ẹni tí ń pa ọ́ mọ́ kò ní tòògbé. Wò ó, ẹni tí ń pa Israẹli mọ́ kò ní tòògbé, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sùn. OLUWA ni olùpamọ́ rẹ. OLUWA yóo ṣíji bò ọ́ ní apá ọ̀tún rẹ. Oòrùn kò ní ṣe ọ́ léṣe lọ́sàn-án, bẹ́ẹ̀ ni òṣùpá kò ní pa ọ́ lára lóru. OLUWA óo dáàbò bò ọ́ lọ́wọ́ gbogbo ibi, yóo pa ọ́ mọ́. OLUWA yóo pa àlọ ati ààbọ̀ rẹ mọ́, láti ìsinsìnyìí lọ ati títí lae. Inú mi dùn nígbà tí wọ́n wí fún mi pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí ilé OLUWA.” A ti tẹsẹ̀ bọ inú ìgboro rẹ, Jerusalẹmu. Jerusalẹmu, ìlú ńlá tí a kọ́, tí gbogbo rẹ̀ já pọ̀ di ọ̀kan. Níbi tí àwọn ẹ̀yà, àní, àwọn ẹ̀yà eniyan OLUWA máa ń gòkè lọ, láti dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí a pa fún Israẹli. Níbẹ̀ ni a tẹ́ ìtẹ́ ìdájọ́ sí, àní, ìtẹ́ ìdájọ́ àwọn ọba ìdílé Dafidi. Gbadura fún alaafia Jerusalẹmu! “Yóo dára fún àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ! Kí alaafia ó wà ninu rẹ, kí ìbàlẹ̀ àyà wà ninu ilé ìṣọ́ rẹ.” Nítorí ti àwọn ará ati àwọn ẹlẹgbẹ́ mi, n óo wí pé, “Kí alaafia ó wà ninu rẹ.” Nítorí ti ilé OLUWA, Ọlọrun wa, èmi óo máa wá ire rẹ. Ìwọ ni mo gbé ojú sókè sí, ìwọ tí o gúnwà ní ọ̀run. Wò ó, bí iranṣẹkunrin ti máa ń wo ojú oluwa rẹ̀, tí iranṣẹbinrin sì máa ń wo ojú oluwa rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni à ń wo ojú OLUWA, Ọlọrun wa, títí tí yóo fi ṣàánú wa. Ṣàánú wa, OLUWA, ṣàánú wa, ẹ̀gàn yìí ti pọ̀ jù! Ẹ̀gàn àwọn onírera ti pọ̀ jù fún wa; yẹ̀yẹ́ àwọn onigbeeraga sì ti sú wa. Tí kì í bá ṣe pé OLUWA tí ó wà lẹ́yìn wa, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ wí pé, “Tí kì í bá ṣe pé OLUWA tí ó wà lẹ́yìn wa nígbà tí ọmọ aráyé gbógun tì wá, wọn ìbá gbé wa mì láàyè, nígbà tí inú bí wọn sí wa; àgbàrá ìbá ti gbá wa lọ, ìṣàn omi ìbá ti bò wá mọ́lẹ̀; ìgbì omi ìbá ti gbé wa mì.” Ọpẹ́ ni fún OLUWA, tí kò fi wá ṣe ẹran ìjẹ fún wọn. A ti yọ, bí ẹyẹ tí ó yọ ninu okùn apẹyẹ: okùn ti já; àwa sì ti yọ. Ọ̀dọ̀ OLUWA ni ìrànlọ́wọ́ wa ti wá, ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé. Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA dàbí òkè Sioni, tí ẹnikẹ́ni kò lè ṣí nídìí, ṣugbọn tí ó wà títí lae. Bí òkè ńlá ti yí Jerusalẹmu ká, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA yí àwọn eniyan rẹ̀ ká, láti ìsinsìnyìí lọ ati títí lae. Eniyan burúkú kò ní ní àṣẹ lórí ilẹ̀ àwọn olódodo, kí àwọn olódodo má baà dáwọ́ lé ibi. OLUWA, ṣe oore fún àwọn eniyan rere, ati fún àwọn olódodo. Ṣugbọn OLUWA yóo fi irú ìyà àwọn aṣebi jẹ àwọn tí ó yà sí ọ̀nà àìtọ́. Alaafia fún Israẹli! Nígbà tí OLUWA kó àwọn ìgbèkùn Sioni pada, ó dàbí àlá lójú wa. Ẹ̀rẹ̀kẹ́ wa kún fún ẹ̀rín, a sì kọrin ayọ̀, nígbà náà ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ń wí pé, “OLUWA mà ṣe nǹkan ńlá fún àwọn eniyan yìí!” Lóòótọ́, OLUWA ṣe nǹkan ńlá fún wa, nítorí náà à ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀. Dá ire wa pada, OLUWA, bí ìṣàn omi ní ipadò aṣálẹ̀ Nẹgẹbu. Àwọn tí ń fọ́n irúgbìn pẹlu omi lójú, jẹ́ kí wọn kórè rẹ̀ tayọ̀tayọ̀. Ẹni tí ń gbé irúgbìn lọ sí oko tẹkúntẹkún, yóo ru ìtí ọkà pada sílé tayọ̀tayọ̀. Bí OLUWA kò bá kọ́ ilé, asán ni wahala àwọn tí ń kọ́ ọ. Bí OLUWA kò bá ṣọ́ ìlú, asán ni àìsùn àwọn aṣọ́de. Asán ni kí á jí ní òwúrọ̀ kutukutu, kí á tún pẹ́ títí kí á tó sùn. Asán ni kí á máa fi làálàá wá oúnjẹ; nítorí pé OLUWA a máa fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ ní oorun sùn. Wò ó! Ẹ̀bùn OLUWA ni ọmọ; òun ní fi oyún inú ṣìkẹ́ eniyan. Bí ọfà ti rí lọ́wọ́ jagunjagun, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ìgbà òwúrọ̀ ẹni. Ayọ̀ ń bẹ fun ẹni tí apó rẹ̀ kún fún wọn. Ojú kò ní tì í nígbà tí ó bá ń bá àwọn ọ̀tá rẹ̀ rojọ́ lẹ́nu bodè. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bẹ̀rù OLÚWA, tí ó sì ń tẹ̀lé ìlànà rẹ̀. O óo jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, ayọ̀ ń bẹ fún ọ, yóo sì dára fún ọ. Aya rẹ yóo dàbí àjàrà eléso pupọ ninu ilé rẹ; bí ọmọ tií yí igi olifi ká, ni àwọn ọmọ rẹ yóo yí tabili oúnjẹ rẹ ká. Wò ó, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA yóo kẹ́ ẹni tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Kí OLUWA bukun ọ láti Sioni! Kí o máa rí ire Jerusalẹmu ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. Kí o máa rí arọmọdọmọ rẹ. Kí alaafia máa wà ní Israẹli. Ọpọlọpọ ìgbà ni wọ́n ti ń pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi. Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ wí pé, “Ọpọlọpọ ìgbà ni wọ́n ti ń pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi, sibẹ, wọn kò borí mi.” Wọ́n to ẹgba sí mi lẹ́yìn, gbogbo ẹ̀yìn mi lé bíi poro oko. Ṣugbọn olódodo ni OLUWA, ó ti gé okùn àwọn eniyan burúkú. Ojú yóo ti gbogbo àwọn tí ó kórìíra Sioni, a óo lé wọn pada sẹ́yìn. Wọn óo dàbí koríko tí ó hù lórí òrùlé, tí kì í dàgbà kí ó tó gbẹ. Kò lè kún ọwọ́ ẹni tí ń pa koríko; kò sì lè kún ọwọ́ ẹni tí ń di koríko ní ìtí. Àwọn èrò ọ̀nà kò sì ní kí ẹni tí ń gé e pé: “OLUWA óo fèrè síṣẹ́ o! Ẹ kúuṣẹ́, OLUWA óo fèrè sí i.” Ninu ìṣòro ńlá ni mò ń ké pè ọ́, OLUWA! OLUWA, gbóhùn mi, dẹtí sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi. Bí OLUWA bá ń sàmì ẹ̀ṣẹ̀, ta ló lè yege? Ṣugbọn ní ìkáwọ́ rẹ ni ìdáríjì wà, kí á lè máa bẹ̀rù rẹ. Mo gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, àní, mo gbé ọkàn mi lé e, mo sì ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ̀. Mò ń retí rẹ, OLUWA, ju bí àwọn aṣọ́de ti máa ń retí kí ilẹ̀ mọ́ lọ, àní, ju bí àwọn aṣọ́de, ti máa ń retí pé kí ilẹ̀ mọ́. Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ ní ìrètí ninu OLUWA! Nítorí pé ní ìkáwọ́ rẹ̀ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ wà, ní ìkáwọ́ rẹ̀ sì ni ìràpadà kíkún wà. Òun óo sì ra Israẹli pada kúrò ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. OLUWA, n kò ṣe ìgbéraga, bẹ́ẹ̀ ni ojú mi kò gbé sókè. N ò dáwọ́ lé nǹkan ńláńlá, n ò sì dá àrà tí ó jù mí lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, mo fi ara mi lọ́kàn balẹ̀, mo dákẹ́ jẹ́ẹ́, bí ọmọ ọwọ́ tíí dákẹ́ jẹ́ẹ́ láyà ìyá rẹ̀. Ọkàn mi balẹ̀ bíi ti ọmọ ọwọ́ tó dákẹ́ jẹ́ẹ́. Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ ní ìrètí ninu OLUWA, láti ìsinsìnyìí lọ ati títí laelae. OLUWA, ranti gbogbo ìyà tí Dafidi fara dà. Ranti bí ó ṣe búra fún OLUWA, tí ó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ fún ìwọ Alágbára, Ọlọrun Jakọbu, tí ó ní, “N kò ní wọ inú ilé mi, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní bọ́ sí orí ibùsùn mi; n kò ní sùn, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní tòògbé, títí tí n óo fi wá ààyè fún OLUWA, àní, tí n óo fi pèsè ibùgbé fún ìwọ Alágbára, Ọlọrun Jakọbu.” A gbúròó rẹ̀ ní Efurata, a rí i ní oko Jearimu. “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí ibùgbé rẹ̀; ẹ jẹ́ kí á lọ wólẹ̀ níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀.” Dìde, OLUWA, lọ sí ibi ìsinmi rẹ, tìwọ ti àpótí agbára rẹ. Jẹ́ kí àwọn alufaa rẹ wọ ẹ̀wù òdodo, kí àwọn eniyan mímọ́ rẹ sì máa kọrin ayọ̀. Nítorí ti Dafidi, iranṣẹ rẹ, má jẹ́ kí ẹni tí a fi òróró rẹ yàn yíjú kúrò lára rẹ. OLUWA ti ṣe ìbúra tí ó dájú fún Dafidi, èyí tí kò ní yipada; ó ní, “Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ ni n óo gbé ka orí ìtẹ́ rẹ. Bí àwọn ọmọ rẹ bá pa majẹmu mi mọ́, tí wọ́n sì tẹ̀lé ìlànà tí n óo fi lélẹ̀ fún wọn, àwọn ọmọ tiwọn náà óo jókòó lórí ìtẹ́ rẹ títí lae.” Nítorí OLUWA ti yan Sioni; ó fẹ́ ẹ fún ibùjókòó rẹ̀: Ó ní, “Ìhín ni ibi ìsinmi mi títí lae, níhìn-ín ni n óo máa gbé, nítorí pé ó wù mí. N óo bù sí oúnjẹ rẹ̀ lọpọlọpọ; n óo fi oúnjẹ tẹ́ àwọn aláìní ibẹ̀ lọ́rùn. N óo gbé ẹ̀wù ìgbàlà wọ àwọn alufaa rẹ̀, àwọn eniyan mímọ́ rẹ̀ yóo sì kọrin ayọ̀. Níbẹ̀ ni n óo ti fún Dafidi ní agbára; mo ti gbé àtùpà kalẹ̀ fún ẹni tí mo fi òróró yàn. N óo da ìtìjú bo àwọn ọ̀tá rẹ̀ bí aṣọ, ṣugbọn adé orí rẹ̀ yóo máa tàn yinrinyinrin.” Ó dára, ó sì dùn pupọ, bí àwọn ará bá ń gbé pọ̀ ní ìrẹ́pọ̀. Ó dàbí òróró iyebíye tí a dà síni lórí, tí ó ṣàn dé irùngbọ̀n; bí ó ti ṣàn dé irùngbọ̀n Aaroni, àní, títí dé ọrùn ẹ̀wù rẹ̀. Ó dàbí ìrì òkè Herimoni, tí ó sẹ̀ sórí òkè Sioni. Níbẹ̀ ni OLUWA ti ṣe ìlérí ibukun, àní, ìyè ainipẹkun. Ẹ wá, ẹ yin OLUWA, gbogbo ẹ̀yin iranṣẹ rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin tí ń sìn ín ninu ilé rẹ̀ lóru. Ẹ gbé ọwọ́ yín sókè, kí ẹ gbadura ninu ilé mímọ́ rẹ̀, kí ẹ sì yin OLUWA. Kí OLUWA tí ó dá ọ̀run ati ayé bukun yín láti Sioni wá. Ẹ yin OLUWA. Ẹ yin orúkọ OLUWA; ẹ yìn ín, ẹ̀yin iranṣẹ rẹ̀, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń jọ́sìn ninu ilé OLUWA, tí ẹ wà ní àgbàlá ilé Ọlọrun wa. Ẹ yin OLUWA, nítorí pé ó ṣeun; ẹ kọrin ìyìn sí i, nítorí pé olóore ọ̀fẹ́ ni. Nítorí pé OLUWA ti yan Jakọbu fún ara rẹ̀, ó ti yan Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀. Èmi mọ̀ pé OLUWA tóbi, ati pé ó ju gbogbo oriṣa lọ. Bí ó ti wu OLUWA ni ó ń ṣe lọ́run ati láyé, ninu òkun ati ninu ibú. Òun ló gbá ìkùukùu jọ láti òpin ilẹ̀ ayé, ó fi mànàmáná fún òjò, ó sì mú afẹ́fẹ́ jáde láti inú ilé ìṣúra rẹ̀. Òun ló pa àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Ijipti, ati teniyan ati tẹran ọ̀sìn. Ẹni tí ó rán iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu sí ilẹ̀ Ijipti, ó rán sí Farao ati gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀. Ẹni tí ó pa orílẹ̀-èdè pupọ run; ó pa àwọn ọba alágbára: Sihoni ọba àwọn Amori, Ogu ọba Baṣani, ati gbogbo ọba ilẹ̀ Kenaani. Ó pín ilẹ̀ wọn fún àwọn eniyan rẹ̀; ó pín in fún Israẹli bí ohun ìní wọn. OLUWA, orúkọ rẹ yóo wà títí lae, òkìkí rẹ óo sì máa kàn títí ayé. OLUWA yóo dá àwọn eniyan rẹ̀ láre, yóo sì ṣàánú àwọn iranṣẹ rẹ̀. Wúrà ati fadaka ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù fi ṣe oriṣa wọn, iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni wọ́n. Wọ́n lẹ́nu, ṣugbọn wọn kò lè sọ̀rọ̀, wọ́n lójú, ṣugbọn wọn kò lè ríran. Wọ́n létí, ṣugbọn wọn kò lè gbọ́ràn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí èémí kan ní ẹnu wọn. Àwọn tí ń ṣe wọ́n yóo dàbí wọn, ati gbogbo àwọn tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé wọn. Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin ará ilé Aaroni, ẹ yin OLUWA! Ẹ̀yin ará ilé Lefi, ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ yìn ín! Ẹ yin OLUWA ní Sioni, ẹni tí ń gbé Jerusalẹmu! Ẹ yin OLUWA! Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun tí ó ju gbogbo àwọn oriṣa lọ, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA tí ó ju gbogbo àwọn oluwa lọ, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Òun nìkan ṣoṣo ní ń ṣe iṣẹ́ ìyanu ńlá, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lé orí omi, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ó dá oòrùn láti máa ṣe àkóso ọ̀sán, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ó dá òṣùpá ati ìràwọ̀ láti máa ṣe àkóso òru, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹni tí ó pa àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Ijipti, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ó sì kó àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò láàrin wọn, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Pẹlu ipá ati ọwọ́ líle ni ó fi kó wọn jáde, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹni tí ó pín Òkun Pupa sí meji, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ó sì mú àwọn ọmọ Israẹli kọjá láàrin rẹ̀, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ṣugbọn ó bi Farao ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ṣubú ninu Òkun Pupa, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹni tí ó mú àwọn eniyan rẹ̀ la aṣálẹ̀ já, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ẹni tí ó pa àwọn ọba ńlá, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ó sì pa àwọn ọba olókìkí, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; Sihoni ọba àwọn Amori, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ati Ogu ọba Baṣani, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ó pín ilẹ̀ wọn fún àwọn eniyan rẹ̀, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ó fún àwọn ọmọ Israẹli, iranṣẹ rẹ̀, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Òun ni ó ranti wa ní ipò ìrẹ̀lẹ̀ wa, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ó sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹni tí ó pèsè oúnjẹ fún gbogbo ẹ̀dá alààyè, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun ọ̀run, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Lẹ́bàá odò Babiloni ni a jókòó, tí a sọkún, nígbà tí a ranti Sioni. Lára igi wilo níbẹ̀ ni a fi hapu wa kọ́ sí, nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn tí ó kó wa ní ìgbèkùn ti ní kí á kọrin fún àwọn. Àwọn tí ó ń pọ́n wa lójú sọ pé kí á dá àwọn lárayá, wọ́n ní, “Ẹ kọ orin Sioni kan fún wa.” Báwo ni a óo ṣe kọ orin OLUWA ní ilẹ̀ àjèjì? Jerusalẹmu, bí mo bá gbàgbé rẹ, kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó rọ. Kí ahọ́n mi lẹ̀ mọ́ èrìgì mi, bí n kò bá ranti rẹ, bí n kò bá sì fi Jerusalẹmu ṣe olórí ayọ̀ mi. OLUWA, ranti ohun tí àwọn ará Edomu ṣe nígbà tí Jerusalẹmu bọ́ sọ́wọ́ ọ̀tá, tí wọn ń pariwo pé, “Ẹ wó o palẹ̀! Ẹ wó o palẹ̀! Ẹ wó o títí dé ìpìlẹ̀ rẹ̀.” Babiloni! Ìwọ apanirun! Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbẹ̀san lára rẹ, fún gbogbo ohun tí o ti ṣe sí wa! Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá kó àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ, tí ó ṣán wọn mọ́ àpáta. N óo máa yìn ọ́ tọkàntọkàn OLUWA, lójú àwọn oriṣa ni n óo máa kọrin ìyìn sí ọ. Ní ìtẹríba, n óo kọjú sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ, n óo sì máa yin orúkọ rẹ, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ rẹ, nítorí pé o gbé ọ̀rọ̀ rẹ ati orúkọ rẹ ga ju ohunkohun lọ. Ní ọjọ́ tí mo ké pè ọ́, o dá mi lóhùn, o sì fún mi ní agbára kún agbára. OLUWA, gbogbo ọba ayé ni yóo máa yìn ọ́, nítorí pé wọ́n ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ. Wọn óo sì máa kọrin nípa iṣẹ́ OLUWA, nítorí pé ògo OLUWA tóbi. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA ga lọ́lá, ó ka àwọn onírẹ̀lẹ̀ sí, ṣugbọn ó mọ àwọn onigbeeraga lókèèrè. Bí mo tilẹ̀ wà ninu ìpọ́njú, sibẹ, o dá mi sí; o dojú ìjà kọ ibinu àwọn ọ̀tá mi, o sì fi ọwọ́ agbára rẹ gbà mí. OLUWA yóo mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ lórí mi, OLUWA, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Má kọ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ sílẹ̀. OLUWA, o ti yẹ̀ mí wò, o sì mọ̀ mí. O mọ ìgbà tí mo jókòó, ati ìgbà tí mo dìde; o mọ èrò ọkàn mi láti òkèèrè réré. O yẹ ìrìn ẹsẹ̀ mi ati àbọ̀sinmi mi wò; gbogbo ọ̀nà mi ni o sì mọ̀. Kódà kí n tó sọ ọ̀rọ̀ jáde lẹ́nu, OLUWA, o ti mọ gbogbo nǹkan tí mo fẹ́ sọ patapata. O pa mí mọ́, níwájú ati lẹ́yìn; o gbé ọwọ́ ààbò rẹ lé mi. Irú ìmọ̀ yìí jẹ́ ohun ìyanu fún mi, ó ga jù, ojú mi kò tó o. Níbo ni mo lè sá lọ, tí ẹ̀mí rẹ kò ní sí níbẹ̀? Níbo ni mo lè sá gbà tí ojú rẹ kò ní tó mi? Ǹ báà gòkè re ọ̀run, o wà níbẹ̀! Bí mo sì tẹ́ ibùsùn mi sí isà òkú, n óo bá ọ níbẹ̀. Ǹ báà hu ìyẹ́, kí n fò lọ sí ibi ojúmọ́ ti ń mọ́ wá, kí n lọ pàgọ́ sí ibi tí òkun pin sí, níbẹ̀ gan-an, ọwọ́ rẹ ni yóo máa tọ́ mi, tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóo sì dì mí mú. Bí mo bá wí pé kí kìkì òkùnkùn bò mí mọ́lẹ̀, kí ọ̀sán di òru fún mi, òkùnkùn gan-an kò ṣú jù fún ọ; òru mọ́lẹ̀ bí ọ̀sán; lójú rẹ, ìmọ́lẹ̀ kò yàtọ̀ sí òkùnkùn. Nítorí ìwọ ni o dá inú mi, ìwọ ni o sọ mí di odidi ní inú ìyá mi. Mo yìn ọ́, nítorí pé ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ati ẹni ìyanu ni ọ́; ìyanu ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ! O mọ̀ mí dájú. Nígbà tí à ń ṣẹ̀dá egungun mi lọ́wọ́ ní ìkọ̀kọ̀, tí ẹlẹ́dàá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣọnà sí mi lára ní àṣírí, kò sí èyí tí ó pamọ́ fún ọ. Kí á tó dá mi tán ni o ti rí mi, o ti kọ iye ọjọ́ tí a pín fún mi sinu ìwé rẹ, kí ọjọ́ ayé mi tilẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ rárá. Ọlọrun, iyebíye ni èrò rẹ lójú mi! Wọ́n pọ̀ pupọ ní iye. Bí mo bá ní kí n kà wọ́n, wọ́n pọ̀ ju iyanrìn lọ; nígbà tí mo bá sì jí, ọ̀dọ̀ rẹ náà ni n óo wà. Ọlọrun, ò bá jẹ́ pa àwọn eniyan burúkú, kí àwọn apànìyàn sì kúrò lọ́dọ̀ mi. Wọ́n ń sọ ọ̀rọ̀ ọ̀tẹ̀ nípa rẹ, àwọn ọ̀tá rẹ ń ba orúkọ rẹ jẹ́. OLUWA, mo kórìíra àwọn tí ó kórìíra rẹ; mo sì kẹ́gàn àwọn tí ń dìtẹ̀ sí ọ? Mo kórìíra wọn dé òpin; ọ̀tá ni mo kà wọ́n kún. Wádìí mi, Ọlọrun, kí o mọ ọkàn mi; yẹ̀ mí wò, kí o sì mọ èrò ọkàn mi. Wò ó bí ọ̀nà ibi kan bá wà tí mò ń tọ̀, kí o sì tọ́ mi sí ọ̀nà ayérayé. OLUWA, gbà mí lọ́wọ́ àwọn ẹni ibi; dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá; àwọn tí ó ń pète ibi lọ́kàn wọn, tí wọ́n sì ń dá ogun sílẹ̀ nígbàkúùgbà, Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn, ó mú bí ahọ́n ejò; oró paramọ́lẹ̀ sì ń bẹ ninu eyín wọn. OLUWA, ṣọ́ mi lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú; dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá, tí ó ń gbìmọ̀ láti ré mi lẹ́pa. Àwọn agbéraga ti dẹ tàkúté sílẹ̀ dè mí, wọ́n dẹ àwọ̀n sílẹ̀ fún mi; wọ́n sì dẹ okùn sílẹ̀ fún mi lẹ́bàá ọ̀nà. Mo wí fún OLUWA pé, “Ìwọ ni Ọlọrun mi.” OLUWA, tẹ́tí sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi. OLUWA, OLUWA mi, alágbára tíí gbani là, ìwọ ni o dáàbò bò mí ní ọjọ́ ogun. OLUWA, má jẹ́ kí ọwọ́ àwọn eniyan burúkú tẹ ohun tí wọn ń wá; má jẹ́ kí èrò ọkàn wọn ṣẹ. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ibi ẹnu àwọn tí ó yí mi ká dà lé wọn lórí. Jẹ́ kí ẹ̀yinná dà lé wọn lórí; jẹ́ kí wọn já sí kòtò, kí wọn má lè yọ. Má jẹ́ kí abanijẹ́ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ lórí ilẹ̀ náà; jẹ́ kí oníwà ipá ko àgbákò kíákíá. Mo mọ̀ pé OLUWA yóo gba ọ̀ràn olùpọ́njú rò, yóo sì ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn aláìní. Dájúdájú, àwọn olódodo yóo máa fi ọpẹ́ fún ọ; àwọn olóòótọ́ yóo sì máa gbé níwájú rẹ. OLUWA, mo ké pè ọ́, tètè wá dá mi lóhùn, tẹ́tí sí ohùn mi nígbà tí mo bá ń ké pè ọ́. Jẹ́ kí adura mi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ bíi turari, sì jẹ́ kí ọwọ́ adura tí mo gbé sókè dàbí ẹbọ àṣáálẹ́. OLUWA, fi ìjánu sí mi ní ẹnu, sì ṣe aṣọ́nà ètè mi. Má jẹ́ kí ọkàn mi fà sí ibi, má sì jẹ́ kí n lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ìkà. Má jẹ́ kí n bá àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ rìn pọ̀, má sì jẹ́ kí n jẹ ninu oúnjẹ àdídùn wọn. N ò kọ̀ kí ẹni rere bá mi wí, n ò kọ̀ kí ó nà mí; kí ó ṣá ti fi ìfẹ́ bá mi wí. Ṣugbọn má jẹ́ kí eniyan burúkú tilẹ̀ ta òróró sí mi lórí, nítorí pé nígbàkúùgbà ni mò ń fi adura tako ìwà ibi wọn. Nígbà tí ọwọ́ àwọn tí yóo dá wọn lẹ́bi bá tẹ̀ wọ́n, wọn óo gbà pé, òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ OLUWA. Bí òkúta tí eniyan là, tí ó fọ́ yángá-yángá sílẹ̀, ni a óo fọ́n egungun wọn ká sí ẹnu ibojì. Ṣugbọn ìwọ ni mo gbójúlé, OLUWA, Ọlọrun. Ìwọ ni asà mi, má fi mí sílẹ̀ láìní ààbò. Pa mí mọ́ ninu ewu tàkúté, ati ti okùn tí àwọn aṣebi dẹ sílẹ̀ dè mí. Jẹ́ kí àwọn eniyan burúkú ṣubú sinu àwọ̀n ara wọn, kí èmi sì lọ láìfarapa. Mo ké pe OLUWA, mo gbé ohùn ẹ̀bẹ̀ sókè sí i. Mo tú ẹ̀dùn ọkàn mi palẹ̀ níwájú rẹ̀, mo sọ ìṣòro mi fún un. Nígbà tí ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì, ó mọ ọ̀nà tí mo lè gbà. Wọ́n ti dẹ tàkúté sílẹ̀ fún mi ní ọ̀nà tí mò ń rìn. Mo wo ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún mi yíká, mo rí i pé kò sí ẹni tí ó náání mi; kò sí ààbò fún mi, ẹnikẹ́ni kò sì bìkítà fún mi. Mo ké pè ọ́, OLUWA, mo ní, “Ìwọ ni ààbò mi, ìwọ ni ìpín mi lórí ilẹ̀ alààyè.” Gbọ́ igbe mi; nítorí wọ́n ti rẹ̀ mí sílẹ̀ patapata. Gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi, nítorí pé wọ́n lágbára jù mí lọ. Yọ mí kúrò ninu ìhámọ́, kí n lè yin orúkọ rẹ lógo. Àwọn olódodo yóo yí mi ká, nítorí ọpọlọpọ oore tí o óo ṣe fún mi. OLUWA, gbọ́ adura mi; fetí sí ẹ̀bẹ̀ mi! Dá mi lóhùn ninu òtítọ́ ati òdodo rẹ. Má dá èmi ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ lẹ́jọ́, nítorí pé kò sí ẹ̀dá alààyè tí ẹjọ́ rẹ̀ lè tọ́ níwájú rẹ. Ọ̀tá ti lé mi bá, ó ti lù mí bolẹ̀; ó jù mí sinu òkùnkùn, bí ẹni tí ó ti kú tipẹ́tipẹ́. Nítorí náà ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì; ọkàn mi sì pòrúúruù. Mo ranti ìgbà àtijọ́, mo ṣe àṣàrò lórí gbogbo ohun tí o ti ṣe, mo sì ronú lórí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Mo na ọwọ́ sí ọ fún ìrànlọ́wọ́; bí òùngbẹ omi í tií gbẹ ilẹ̀ gbígbẹ, bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi. OLUWA, yára dá mi lóhùn! Ẹ̀mí mi ti fẹ́rẹ̀ pin! Má fara pamọ́ fún mi, kí n má baà dàbí àwọn tí ó ti lọ sinu isà òkú. Jẹ́ kí n máa ranti ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ láràárọ̀, nítorí ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé. Kọ́ mi ní ọ̀nà tí n óo máa rìn, nítorí pé ìwọ ni mo gbójú sókè sí. OLUWA, gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi; ìwọ ni mo sá di. Kọ́ mi láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ, nítorí pé ìwọ ni Ọlọrun mi. Jẹ́ kí ẹ̀mí rere rẹ máa tọ́ mi ní ọ̀nà tí ó tọ́. Nítorí ti orúkọ rẹ, OLUWA, dá mi sí; ninu òtítọ́ rẹ, yọ mí ninu ìpọ́njú. Ninu ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, pa àwọn ọ̀tá mi, kí o sì pa gbogbo àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi run, nítorí pé iranṣẹ rẹ ni mí. Ìyìn ni fún OLUWA, àpáta mi, ẹni tí ó kọ́ mi ní ìjà jíjà, tí ó kọ́ mi ní iṣẹ́ ogun. Òun ni àpáta mi, ààbò mi, odi mi, olùdáǹdè mi, asà mi, ẹni tí mo sá di. Òun ni ó tẹrí àwọn eniyan ba lábẹ́ rẹ̀. OLUWA, kí ni eniyan jẹ́, tí o fi ń náání rẹ̀? Kí sì ni ọmọ eniyan tí o fi ń ranti rẹ̀? Eniyan dàbí èémí, ọjọ́ ayé rẹ̀ sì dàbí òjìji tí ń kọjá lọ. OLUWA, fa ojú ọ̀run wá sílẹ̀, kí o sì sọ̀kalẹ̀ wá, fọwọ́ kan àwọn òkè ńlá, kí wọ́n máa rú èéfín. Jẹ́ kí mànàmáná kọ, kí o sì tú wọn ká, ta ọfà rẹ, kí o tú wọn ká. Na ọwọ́ rẹ sílẹ̀ láti òkè, kí o yọ mí ninu ibú omi; kí o sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn àjèjì, tí ẹnu wọn kún fún irọ́, tí ọwọ́ ọ̀tún wọn sì kún fún èké. Ọlọrun, n óo kọ orin titun sí ọ, n óo fi hapu olókùn mẹ́wàá kọrin sí ọ. Ìwọ ni ò ń fún àwọn ọba ní ìṣẹ́gun, tí o sì gba Dafidi, iranṣẹ rẹ, là. Gbà mí lọ́wọ́ idà ìkà, gbà mí lọ́wọ́ àwọn àjèjì, tí ẹnu wọ́n kún fún irọ́, tí ọwọ́ ọ̀tún wọn sì kún fún èké. Ní ìgbà èwe àwọn ọdọmọkunrin wa, jẹ́ kí wọ́n dàbí igi tí a gbìn tí ó dàgbà, kí àwọn ọdọmọbinrin wa dàbí òpó igun ilé, tí a ṣiṣẹ́ ọnà sí bíi ti ààfin ọba. Kí àká wa kún fún oniruuru oúnjẹ, kí àwọn aguntan wa bí ẹgbẹẹgbẹrun, àní, ẹgbẹẹgbaarun ninu pápá oko wa. Kí àwọn mààlúù wa lóyún, kí wọ́n má rọ́nú, kí wọ́n má bí òkúmọ; kí ó má sí ariwo àjálù ní ìgboro wa. Ayọ̀ ń bẹ fún orílẹ̀-èdè tí ó ní irú ibukun yìí; ayọ̀ ń bẹ fún orílẹ̀-èdè tí OLUWA jẹ́ Ọlọrun wọn. Èmi óo gbé ọ ga, Ọlọrun mi, Ọba mi, n óo máa yin orúkọ rẹ lae ati laelae. Lojoojumọ ni n óo máa yìn ọ́, tí n óo máa yin orúkọ rẹ lae ati laelae. OLUWA tóbi, ìyìn sì yẹ ẹ́ lọpọlọpọ; àwámárìídìí ni títóbi rẹ̀. Láti ìran dé ìran ni a óo máa yin iṣẹ́ rẹ, tí a óo sì máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ agbára ńlá rẹ. Èmi óo máa ṣe àṣàrò lórí ẹwà ògo ọlá ńlá rẹ, ati iṣẹ́ ìyanu rẹ. Eniyan óo máa kéde iṣẹ́ agbára rẹ tí ó yani lẹ́nu, èmi óo sì máa polongo títóbi rẹ. Wọn óo máa pòkìkí bí oore rẹ ti pọ̀ tó, wọn óo sì máa kọrin sókè nípa òdodo rẹ. Aláàánú ni OLUWA, olóore sì ni; kì í yára bínú, ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀. OLUWA ṣeun fún gbogbo eniyan, àánú rẹ̀ sì ń bẹ lórí gbogbo ohun tí ó dá. OLUWA, gbogbo ohun tí o dá ni yóo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, àwọn eniyan mímọ́ rẹ yóo sì máa yìn ọ́. Wọn óo máa ròyìn ògo ìjọba rẹ, wọn óo sì máa sọ nípa agbára rẹ, láti mú àwọn eniyan mọ agbára rẹ, ati ẹwà ògo ìjọba rẹ. Ìjọba ayérayé ni ìjọba rẹ, yóo sì máa wà láti ìran dé ìran. Olóòótọ́ ni OLUWA ninu gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀, olóore ọ̀fẹ́ sì ni ninu gbogbo ìṣe rẹ̀. OLUWA gbé gbogbo àwọn tí ń ṣubú lọ dìde, ó sì gbé gbogbo àwọn tí a tẹrí wọn ba nàró. Ojú gbogbo eniyan ń wò ọ́, o sì fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àsìkò. Ìwọ la ọwọ́ rẹ, o sì tẹ́ gbogbo ẹ̀dá alààyè lọ́rùn. Olódodo ni OLUWA ninu gbogbo ọ̀nà rẹ̀, aláàánú sì ni ninu gbogbo ìṣe rẹ̀. OLUWA súnmọ́ gbogbo àwọn tí ń pè é, àní, àwọn tí ń pè é tọkàntọkàn. Ó ń tẹ́ ìfẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ lọ́rùn; ó ń gbọ́ igbe wọn, ó sì ń gbà wọ́n. OLUWA dá gbogbo àwọn tí ó fẹ́ ẹ sí, ṣugbọn yóo pa gbogbo àwọn eniyan burúkú run. Ẹnu mi yóo máa sọ̀rọ̀ ìyìn OLUWA; kí gbogbo ẹ̀dá máa yin orúkọ rẹ̀ lae ati laelae. Ẹ yin OLUWA! Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi. N óo máa yin OLUWA níwọ̀n ìgbà tí mo wà láyé; n óo máa kọrin ìyìn sí Ọlọrun mi níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè. Má gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìjòyè; eniyan ni wọ́n, kò sì sí ìgbàlà lọ́dọ̀ wọn. Bí ẹ̀mí wọn bá ti bọ́, wọn á pada di erùpẹ̀, ní ọjọ́ náà sì ni èrò inú wọn óo di ègbé. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó fi Ọlọrun Jakọbu ṣe olùrànlọ́wọ́ rẹ̀, tí ó gbójú lé OLUWA, Ọlọrun rẹ̀. Ọlọrun tí ó dá ọ̀run ati ayé, òkun ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀; Ọlọrun tíí máa ń pa àdéhùn rẹ̀ mọ́ títí lae, ẹni tíí máa ń dá ẹjọ́ òdodo fún àwọn tí a ni lára; tí ń fún àwọn tí ebi ń pa ní oúnjẹ, OLUWA tíí tú àwọn tí ó wà ninu ìdè sílẹ̀. A máa la ojú àwọn afọ́jú, a máa gbé àwọn tí a tẹrí wọn ba dúró; ó fẹ́ràn àwọn olódodo. OLUWA ni olùṣọ́ àwọn àlejò, òun ni alátìlẹ́yìn àwọn opó ati aláìníbaba, ṣugbọn a máa da ète àwọn eniyan burúkú rú. OLUWA yóo jọba títí lae, Sioni, Ọlọrun rẹ yóo jọba láti ìran dé ìran. Ẹ yin OLUWA. Ẹ yin OLUWA! Nítorí tí ó dára láti máa kọ orin ìyìn sí Ọlọrun wa; nítorí olóore ni, orin ìyìn sì yẹ ẹ́. OLUWA ní ń kọ́ ìlú Jerusalẹmu; òun ni yóo kó àwọn ọmọ Israẹli tí a fọ́n ká jọ. Ó ń tu àwọn tí ọkàn wọn bàjẹ́ ninu, ó sì ń dí ọgbẹ́ wọn. Òun ló mọ iye àwọn ìràwọ̀, òun ló sì fún gbogbo wọn lórúkọ. OLUWA wa tóbi, ó sì lágbára pupọ òye rẹ̀ kò ní ìwọ̀n. OLUWA ní ń gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ró, òun ni ó sì ń sọ àwọn eniyan burúkú di ilẹ̀ẹ́lẹ̀. Ẹ kọ orin ọpẹ́ sí OLUWA, ẹ fi hapu kọ orin dídùn sí Ọlọrun wa. Ẹni tí ó fi ìkùukùu bo ojú ọ̀run, ó pèsè òjò fún ilẹ̀, ó mú koríko hù lórí òkè. Òun ni ó ń fún àwọn ẹranko ní oúnjẹ, tí ó sì ń bọ́ ọmọ ẹyẹ ìwò, tí ó ń ké. Kì í ṣe agbára ẹṣin ni inú rẹ̀ dùn sí, kì í sì í ṣe inú agbára eniyan ni ayọ̀ rẹ̀ wà. Ṣugbọn inú OLUWA dùn sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àwọn tí ó ní ìrètí ninu ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀. Gbé OLUWA ga, ìwọ Jerusalẹmu! Yin Ọlọrun rẹ, ìwọ Sioni! Ó fún ẹnubodè rẹ ní agbára, ó sì bukun àwọn tí ń gbé inú rẹ. Ó jẹ́ kí alaafia wà ní ààlà ilẹ̀ rẹ, ó sì fi oúnjẹ tí ó dára bọ́ ọ lábọ̀ọ́yó. Ó pàṣẹ lórí ilẹ̀ ayé, àṣẹ rẹ̀ sì múlẹ̀ kíá. Ó da òjò dídì bo ilẹ̀ bí ẹ̀gbọ̀n òwú, ó sì fọ́n ìrì dídì ká bí eérú. Ó sọ yìnyín sílẹ̀ bí òkò, ta ni ó lè fara da òtútù rẹ̀? Ó sọ̀rọ̀, wọ́n yọ́, ó fẹ́ afẹ́fẹ́, omi sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn. Ó ṣí ọ̀rọ̀ rẹ̀ payá fún Jakọbu, ó sì fi òfin ati ìlànà rẹ̀ han Israẹli. Kò ṣe bẹ́ẹ̀ fún orílẹ̀-èdè kankan rí, wọn kò sì mọ ìlànà rẹ̀. Ẹ yin OLUWA! Ẹ yin OLUWA! Ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run, ẹ yìn ín lókè ọ̀run. Ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀; ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin ọmọ ogun rẹ̀. Ẹ yìn ín, oòrùn ati òṣùpá; ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ tí ń tàn. Ẹ yìn ín, ọ̀run tí ó ga jùlọ; yìn ín, omi tí ó wà lójú ọ̀run. Ẹ jẹ́ kí wọ́n máa yin orúkọ OLUWA, nítorí nípa àṣẹ rẹ̀ ni a fi dá wọn. Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ títí laelae; ó sì pààlà fún wọn tí wọn kò gbọdọ̀ ré kọjá. Ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin ẹ̀dá ayé, ẹ̀yin erinmi ńláńlá inú òkun ati gbogbo ibú omi; iná ati yìnyín, ati ìrì dídì, ati ẹ̀fúùfù líle tí ń mú àṣẹ rẹ̀ ṣẹ. Ẹ yìn ín, ẹ̀yin òkè ńláńlá ati òkè kéékèèké, ẹ̀yin igi eléso ati igi kedari; ẹ̀yin ẹranko ìgbẹ́ ati ẹran ọ̀sìn, ẹ̀yin ẹ̀dá tí ń fàyà fà ati ẹyẹ tí ń fò. Ẹ yìn ín, ẹ̀yin ọba ayé ati gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹ̀yin ìjòyè ati gbogbo onídàájọ́ ayé; ẹ̀yin ọdọmọkunrin ati ọlọ́mọge, ẹ̀yin ọmọde ati ẹ̀yin àgbààgbà. Ẹ jẹ́ kí wọn yin orúkọ OLUWA, nítorí pé orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ga jù; ògo rẹ̀ sì ga ju ayé ati ọ̀run lọ. Ó ti fún àwọn eniyan rẹ̀ ní agbára, ó sì fún àwọn eniyan rẹ̀ mímọ́ ní ìyìn; ó fún àwọn eniyan Israẹli, tí ó wà lẹ́bàá ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ẹ yin OLUWA! Ẹ yin OLUWA! Ẹ kọ orin titun sí OLUWA, ẹ kọrin ìyìn sí i ninu àwùjọ àwọn olóòótọ́. Kí Israẹli máa yọ̀ ninu Ẹlẹ́dàá rẹ̀, kí àwọn ọmọ Sioni máa fò fún ayọ̀ pé àwọn ní Ọba. Kí wọn máa fi ijó yin orúkọ rẹ̀, kí wọn máa fi ìlù ati hapu kọ orin aládùn sí i. Nítorí pé inú OLUWA dùn sí àwọn eniyan rẹ̀, a sì máa fi ìṣẹ́gun dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé. Kí àwọn olódodo máa ṣògo ninu ọlá; kí wọ́n máa kọrin ayọ̀ lórí ibùsùn wọn. Kí wọn máa fi ohùn wọn yin Ọlọrun; kí idà olójú meji sì wà ní ọwọ́ wọn, láti gbẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, ati láti jẹ àwọn eniyan wọn níyà; láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba orílẹ̀-èdè mìíràn, ati láti fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ de àwọn ọlọ́lá wọn; láti ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀. Ògo gbogbo àwọn olódodo nìyí. Ẹ yin OLUWA! Ẹ yin OLUWA! Ẹ yin Ọlọrun ninu ibi mímọ́ rẹ̀; ẹ yìn ín ninu òfuurufú rẹ̀ tí ó lágbára. Ẹ yìn ín fún iṣẹ́ ńlá rẹ̀; ẹ yìn ín nítorí pé ó tóbi pupọ. Ẹ fi ariwo fèrè yìn ín; ẹ fi fèrè ati hapu yìn ín. Ẹ fi ìlù ati ijó yìn ín; ẹ fi gòjé ati dùùrù yìn ín. Ẹ fi aro olóhùn òkè yìn ín; ẹ fi aro olóhùn gooro yìn ín. Kí gbogbo nǹkan ẹlẹ́mìí yin OLUWA! Ẹ yin OLUWA! Àwọn òwe tí Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli pa, kí àwọn eniyan lè ní ọgbọ́n ati ẹ̀kọ́, kí òye ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ lè yé wọn, láti gba ẹ̀kọ́, tí yóo kọ́ni lọ́gbọ́n, òdodo, ẹ̀tọ́ ati àìṣojúṣàájú, láti kọ́ onírẹ̀lẹ̀ lọ́gbọ́n, kí á sì fi ìmọ̀ ati làákàyè fún ọ̀dọ́, kí ọlọ́gbọ́n lè gbọ́, kí ó sì fi ìmọ̀ kún ìmọ̀ rẹ̀, kí ẹni tí ó ní òye lè ní ìmọ̀ pẹlu. Láti lè mọ òwe ati àkàwé ọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n ati àdììtú ọ̀rọ̀. Ìbẹ̀rù OLUWA ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmọ̀, ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ a máa pẹ̀gàn ọgbọ́n ati ẹ̀kọ́. Ìwọ ọmọ mi, gbọ́ ẹ̀kọ́ baba rẹ, má sì kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ, nítorí pé ẹ̀kọ́ tí wọn bá kọ́ ọ yóo dàbí adé tí ó lẹ́wà lórí rẹ, ati bí ohun ọ̀ṣọ́ ní ọrùn rẹ. Ìwọ ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́, o ò gbọdọ̀ gbà. Bí wọn bá wí pé, “Tẹ̀lé wa ká lọ, kí á lọ sápamọ́ láti paniyan, kí á lúgọ de aláìṣẹ̀, jẹ́ kí á gbé wọn mì láàyè kí á gbé wọn mì lódidi bí isà òkú, a óo rí àwọn nǹkan olówó iyebíye kó, ilé wa yóo sì kún fún ìkógun. Ìwọ ṣá darapọ̀ mọ́ wa, kí á sì jọ lẹ̀dí àpò pọ̀.” Ọmọ mi, má bá wọn kẹ́gbẹ́, má sì bá wọn rìn, nítorí ọ̀nà ibi ni ẹsẹ̀ wọn máa ń yá sí, wọ́n a sì máa yára láti paniyan. Asán ni àwọ̀n tí eniyan dẹ sílẹ̀, nígbà tí ẹyẹ tí a dẹ ẹ́ fún ń woni, ṣugbọn ẹ̀jẹ̀ ara wọn ni irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀ lúgọ dè, ìparun ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n lúgọ tí wọn ń retí. Bẹ́ẹ̀ ni ti àwọn tí wọ́n ń fi ipá kó ọrọ̀ jọ rí, ọrọ̀ tí wọn fi ipá kójọ níí gba ẹ̀mí wọn. Ọgbọ́n ń kígbe ní òpópónà, ó ń pariwo láàrin ọjà, ó ń kígbe lórí odi ìlú, ó ń sọ̀rọ̀ ní àwọn ẹnubodè ìlú, ó ní, “Ẹ̀yin aláìmọ̀kan, ẹ óo ti pẹ́ tó ninu àìmọ̀kan yín? Àwọn pẹ̀gànpẹ̀gàn yóo ti ní inú dídùn pẹ́ tó ninu ẹ̀gàn pípa wọn, tí àwọn òmùgọ̀ yóo sì kórìíra ìmọ̀? Ẹ fetí sí ìbáwí mi, n óo ṣí ọkàn mi payá fun yín, n óo sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi ye yín. Nítorí pé mo ti ké títí, kò sì sí ẹni tí ó gbọ́, mo ti na ọwọ́ si yín ṣugbọn kò sí ẹni tí ó dá mi lóhùn, ẹ ti pa gbogbo ìmọ̀ràn mi tì, ẹ kò sì gbọ́ ọ̀kankan ninu ìbáwí mi. Èmi náà óo sì máa fi yín rẹ́rìn-ín nígbà tí ìdààmú bá dé ba yín, n óo máa fi yín ṣe ẹlẹ́yà nígbà tí ìpayà bá dé ba yín. Nígbà tí ìpayà bá dé ba yín bí ìjì, tí ìdààmú dé ba yín bí ìjì líle, tí ìpọ́njú ati ìrora bò yín mọ́lẹ̀. Ẹ óo ké pè mí nígbà náà, ṣugbọn n kò ní dáhùn. Ẹ óo wá mi láìsinmi, ṣugbọn ẹ kò ní rí mi. Nítorí pé ẹ kórìíra ìmọ̀, ẹ kò sì bẹ̀rù OLUWA. Ẹ kò fẹ́ ìmọ̀ràn mi, ẹ sì kẹ́gàn gbogbo ìbáwí mi. Nítorí náà, ẹ óo jèrè iṣẹ́ yín, ìwà burúkú yín yóo sì di àìsàn si yín lára. Àwọn aláìgbọ́n kú nítorí pé wọn kò gba ẹ̀kọ́ aibikita àwọn òmùgọ̀ ni yóo pa wọ́n run. Ṣugbọn ẹni tí ó gbọ́ tèmi, yóo máa wà láìléwu, yóo máa gbé pẹlu ìrọ̀rùn, láìsí ìpayà ibi.” Ọmọ mi, bí o bá gba ọ̀rọ̀ mi, tí o sì pa òfin mi mọ́, tí o bá ń tẹ́tí rẹ sílẹ̀ sí ọgbọ́n, tí o sì fi ọkàn sí òye, bí o bá kígbe tí o tọrọ òye tí ó jinlẹ̀, tí o gbóhùn sókè tí o bèèrè ìmọ̀, bí o bá wá ọgbọ́n bí ẹni ń wá fadaka, tí o sì wá a bí ẹni ń wá ìṣúra tí a pamọ́, nígbà náà ni ìbẹ̀rù OLUWA yóo yé ọ. O óo sì rí ìmọ̀ Ọlọrun. Nítorí OLUWA níí fún ni ní ọgbọ́n, ẹnu rẹ̀ sì ni òye ati ìmọ̀ ti ń wá. Ó fún àwọn tí wọn dúró ṣinṣin ní ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n, òun ni ààbò fún àwọn tí wọ́n ń rin ọ̀nà ẹ̀tọ́. Ó ń tọ́ wọn sí ìdájọ́ òtítọ́, ó sì ń pa ọ̀nà àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀ mọ́. Nígbà náà ni ìtumọ̀ òdodo ati ẹ̀tọ́ yóo yé ọ ati àìṣe ojuṣaaju, ati gbogbo ọ̀nà rere. Nítorí ọgbọ́n yóo wọnú ọkàn rẹ, ìmọ̀ yóo sì tu ẹ̀mí rẹ lára, ọgbọ́n inú yóo máa ṣọ́ ọ, òye yóo sì máa dáàbò bò ọ́, yóo máa gbà ọ́ lọ́wọ́ ibi ṣíṣe, ati lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́tàn, àwọn tí wọ́n ti kọ ọ̀nà òdodo sílẹ̀ tí wọn sì ń rìn ninu òkùnkùn; àwọn tí wọn ń yọ̀ ninu ìwà ibi tí wọ́n sì ní inú dídùn sí ìyapa ibi; àwọn tí ọ̀nà wọn wọ́, tí wọ́n kún fún ìwà àrékérekè. A óo gbà ọ́ lọ́wọ́ obinrin oníṣekúṣe, àní lọ́wọ́ obinrin onírìnkurìn pẹlu ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn rẹ̀. Ẹni tí ó kọ ọkọ àárọ̀ rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì gbàgbé majẹmu Ọlọrun rẹ̀. Ẹni tí ilé rẹ̀ rì sinu ìparun, tí ọ̀nà rẹ̀ sì wà ninu ọ̀fìn isà òkú. Kò sí ẹni tí ó tọ̀ ọ́ lọ, tí ó pada rí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í tún pada sí ọ̀nà ìyè. Nítorí náà, máa rìn ní ọ̀nà àwọn eniyan rere, sì máa bá àwọn olódodo rìn. Nítorí àwọn tí wọ́n dúró ṣinṣin ni wọn yóo máa gbé ilẹ̀ náà, àwọn olóòótọ́ inú ni yóo máa wà níbẹ̀, ṣugbọn a óo pa ẹni ibi run lórí ilẹ̀ náà, a óo sì fa alárèékérekè tu kúrò níbẹ̀. Ọmọ mi, má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ ọ, sì pa òfin mi mọ́ lọ́kàn rẹ, nítorí wọn óo fún ọ ní ẹ̀mí gígùn ati ọpọlọpọ alaafia. Má jẹ́ kí ìwà ìṣòótọ́ kí ó fi ọ́ sílẹ̀, so àánú ati òtítọ́ mọ́ ọrùn rẹ, kọ wọ́n sí oókan àyà rẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, o óo rí ojurere ati iyì lọ́dọ̀ Ọlọrun ati eniyan. Fi tọkàntọkàn gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, má sì tẹ̀lé ìmọ̀ ara rẹ. Mọ Ọlọrun ní gbogbo ọ̀nà rẹ, yóo sì mú kí ọ̀nà rẹ tọ́. Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara rẹ, bẹ̀rù OLUWA, kí o sì yẹra fún ibi. Tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, yóo jẹ́ ìwòsàn fún ara rẹ, ati ìtura fún egungun rẹ. Fi ohun ìní rẹ bọ̀wọ̀ fún OLUWA pẹlu gbogbo àkọ́so oko rẹ. Nígbà náà ni àká rẹ yóo kún bámúbámú, ìkòkò waini rẹ yóo sì kún àkúnya. Ọmọ mi, má ṣe kẹ́gàn ìtọ́ni OLUWA, má sì ṣe jẹ́ kí ìbáwí rẹ̀ sú ọ. Nítorí ẹni tí OLUWA bá fẹ́ níí báwí gẹ́gẹ́ bí baba tí máa ń bá ọmọ rẹ̀ tí ó bá fẹ́ràn wí. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó wá ọgbọ́n rí, ati ẹni tí ó ní òye. Nítorí èrè rẹ̀ dára ju èrè orí fadaka ati ti wúrà lọ. Ọgbọ́n níye lórí ó ju ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye lọ, kò sí ohun tí o lè fi wé e, ninu gbogbo ohun tí ọkàn rẹ lè fẹ́. Ẹ̀mí gígùn wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ọrọ̀ ati iyì sì wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀. Ọ̀nà rẹ̀ tura pupọ, alaafia sì ni gbogbo ọ̀nà rẹ̀. Igi ìyè ni fún àwọn tí wọ́n rọ̀ mọ́ ọn, ayọ̀ sì ń bẹ fún àwọn tí wọ́n dì í mú ṣinṣin. Ọgbọ́n ni OLUWA fi fi ìdí ayé sọlẹ̀, òye ni ó sì fi dá ọ̀run. Nípa ìmọ̀ rẹ̀ ni ibú fi ń tú omi jáde, tí ìrì fi ń sẹ̀ láti inú ìkùukùu. Ọmọ mi, di ọgbọ́n tí ó yè kooro ati làákàyè mú, má sì ṣe jẹ́ kí wọn bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ, wọ́n yóo jẹ́ ìyè fún ẹ̀mí rẹ, ati ohun ọ̀ṣọ́ ní ọrùn rẹ. Nígbà náà ni o óo máa rìn láìléwu ati láìkọsẹ̀. Bí o bá jókòó, ẹ̀rù kò ní bà ọ́, bí o bá sùn, oorun yóo máa dùn mọ́ ọ. Má bẹ̀rù àjálù òjijì, tabi ìparun àwọn ẹni ibi, nígbà tí ó bá dé bá ọ, nítorí pé, OLUWA ni igbẹkẹle rẹ, kò sì ní jẹ́ kí o ti ẹsẹ̀ bọ tàkúté. Má ṣe fa ọwọ́ ire sẹ́yìn lọ́dọ̀ àwọn tí ó tọ́ sí, nígbà tí ó bá wà ní ìkáwọ́ rẹ láti ṣe é. Má sọ fún aládùúgbò rẹ pé, “Máa lọ ná, n óo fún ọ tí o bá pada wá lọ́la,” nígbà tí ohun tí ó fẹ́ wà lọ́dọ̀ rẹ. Má ṣe gbèrò ibi sí aládùúgbò rẹ tí ń fi inú kan bá ọ gbé. Má ṣe bá ẹnikẹ́ni jà láìnídìí, nígbà tí kò ṣe ọ́ níbi. Má ṣe ìlara ẹni ibi má sì ṣe tẹ̀ sí èyíkéyìí ninu àwọn ọ̀nà rẹ̀. Nítorí OLUWA kórìíra alárèékérekè, ṣugbọn ó ní igbẹkẹle ninu àwọn tí wọn dúró ṣinṣin. Ègún OLUWA wà lórí ìdílé ẹni ibi, ṣugbọn a máa bukun ibùgbé àwọn olódodo. A máa fi àwọn pẹ̀gànpẹ̀gàn ṣe ẹlẹ́yà, ṣugbọn a máa fi ojurere wo àwọn onírẹ̀lẹ̀. Ọlọ́gbọ́n yóo jogún iyì, ṣugbọn ojú yóo ti òmùgọ̀. Ẹ̀yin ọmọ, ẹ gbọ́ ẹ̀kọ́ baba yín, ẹ tẹ́tí sílẹ̀, kí ẹ lè ní ìmọ̀, nítorí pé mo fun yín ní ìlànà rere, ẹ má ṣe kọ ẹ̀kọ́ mi. Nígbà tí mo wà ní ọmọde lọ́dọ̀ baba mi, tí mo jẹ́ ẹni ìkẹ́, ọ̀kan ṣoṣo lọ́wọ́ ìyá mi, baba mi kọ́ mi, ó ní, “Fi ọ̀rọ̀ mi sọ́kàn, pa òfin mi mọ́, kí o lè wà láàyè. Jẹ́ ọlọ́gbọ́n kí o sì ní ìmọ̀. Má gbàgbé, má sì kọ ọ̀rọ̀ sí mi lẹ́nu. Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóo pa ọ́ mọ́, fẹ́ràn rẹ̀, yóo sì dáàbò bò ọ́. Bí o bá fẹ́ gbọ́n, bẹ̀rẹ̀ sí kọ́gbọ́n, ohun yòówù tí o lè tún ní, ọgbọ́n ló jù, nítorí náà jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Gbé ọgbọ́n lárugẹ, yóo sì gbé ọ ga, yóo bu ọlá fún ọ, bí o bá gbà á mọ́ra. Yóo fi nǹkan ọ̀ṣọ́ tí ó lẹ́wà bò ọ́ lórí, yóo sì dé ọ ní adé dáradára.” Gbọ́, ọmọ mi, gba ẹ̀kọ́ mi, kí ẹ̀mí rẹ lè gùn. Mo ti kọ́ ọ ní ọgbọ́n, mo sì ti fẹsẹ̀ rẹ lé ọ̀nà òtítọ́. Nígbà tí o bá ń rìn, o kò ní rí ìdínà, nígbà tí o bá ń sáré, o kò ní fi ẹsẹ̀ kọ. Di ẹ̀kọ́ mú ṣinṣin, má jẹ́ kí ó bọ́, pa á mọ́, nítorí òun ni ìyè rẹ. Má ṣe gba ọ̀nà ẹni ibi, má sì ṣe rin ọ̀nà eniyan burúkú. Yẹra fún un, má tilẹ̀ kọjú sí ọ̀nà ibẹ̀, ṣugbọn gba ibòmíràn, kí o máa bá tìrẹ lọ. Nítorí wọn kì í lè é sùn, bí wọn kò bá tíì ṣe ibi, oorun kì í kùn wọ́n, tí wọn kò bá tíì fa ìṣubú eniyan. Ìkà ṣíṣe ni oúnjẹ wọn, ìwà ipá sì ni ọtí waini wọn. Ṣugbọn ọ̀nà olódodo dàbí ìmọ́lẹ̀ àfẹ̀mọ́júmọ́, tí ń mọ́lẹ̀ sí i láti ìdájí títí tí ilẹ̀ yóo fi mọ́ kedere. Ọ̀nà eniyan burúkú dàbí òkùnkùn biribiri, wọn kò mọ ohun tí wọn yóo dìgbò lù. Ọmọ mi, fetí sí ọ̀rọ̀ mi, tẹ́tí sílẹ̀ sí ohun tí mò ń sọ. Má jẹ́ kí wọn rú ọ lójú, fi wọ́n sọ́kàn. Nítorí pé ìyè ni wọ́n jẹ́ fún àwọn tí ó rí wọn, ati ìwòsàn fún gbogbo ẹran ara wọn. Ṣọ́ra pẹlu èrò ọkàn rẹ, nítorí èrò ọkàn ni orísun ìyè. Má lọ́wọ́ ninu ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ, sì jìnnà sí ọ̀rọ̀ àgàbàgebè. Jẹ́ kí ojú rẹ máa wo ọ̀kánkán, kí o sì kọjú sí ibi tí ò ń lọ tààrà. Kíyèsí ìrìn ẹsẹ̀ rẹ, gbogbo ọ̀nà rẹ yóo sì là. Má ṣe yà sí ọ̀tún tabi sí òsì, yipada kúrò ninu ibi. Ọmọ mi fetí sí ọgbọ́n tí mò ń kọ́ ọ, tẹ́tí rẹ sí òye mi, kí o baà lè ní làákàyè, kí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ lè kún fún ìmọ̀. Nítorí ẹnu alágbèrè obinrin a máa dùn bí oyin, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì tuni lára ju òróró lọ, ṣugbọn níkẹyìn ọ̀rọ̀ rẹ̀ á korò bí iwọ, ẹnu rẹ̀ á sì mú bí idà olójú meji. Ẹsẹ̀ rẹ̀ ń dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ lọ sinu ikú, ìgbésẹ̀ rẹ̀ sì lọ tààrà sinu ibojì. Ó kọ̀ láti rin ọ̀nà ìyè, ọ̀nà rẹ̀ wọ́, kò sì mọ̀. Nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, ẹ má sì kọ ọ̀rọ̀ sí mi lẹ́nu. Ẹ jìnnà sí alágbèrè obinrin, kí ẹ má tilẹ̀ súnmọ́ ẹnu ọ̀nà rẹ̀, kí ẹ má baà gbé ògo yín fún ẹlòmíràn, kí ẹ sì fi ìgbé ayé yín lé aláìláàánú lọ́wọ́. Kí àjèjì má baà jèrè iṣẹ́ yín, kí làálàá rẹ má sì bọ́ sápò àlejò. Kí o má baà kérora nígbẹ̀yìn ayé rẹ, nígbà tí o bá di ìjẹ fún ẹni ẹlẹ́ni nígbà náà ni o óo wí pé, “Kí ló dé tí mo kórìíra ìtọ́ni, tí ọkàn mi sì kẹ́gàn ìbáwí! N kò fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn olùkọ́ mi n kò sì gba ti àwọn tí wọn ń tọ́ mi sọ́nà. Èyí ni ó sún mi dé etí bèbè ìparun, láàrin àwùjọ eniyan.” Ìwọ ọkọ, láti inú àmù rẹ ni kí o ti máa mu omi; omi tí ń sun láti inú kànga rẹ ni kí o máa mu. Kò dára kí orísun rẹ máa ṣàn káàkiri, bí omi àgbàrá ní gbogbo òpópónà. Tìrẹ nìkan ṣoṣo ni kí ó jẹ́, má jẹ́ kí àjèjì bá ọ pín ninu rẹ̀. Jẹ́ kí orísun rẹ ní ibukun, kí inú rẹ sì máa dùn sí iyawo tí o fi àárọ̀ gbé. Olólùfẹ́ rẹ tí ó dára bí abo egbin. Jẹ́ kí ẹwù rẹ̀ máa mú inú rẹ dùn nígbà gbogbo, kí ìfẹ́ rẹ̀ máa mú orí rẹ yá nígbàkúùgbà. Kí ló dé, ọmọ mi, tí ìfẹ́ alágbèrè obinrin yóo fi wọ̀ ọ́ lọ́kàn, tí o óo fi máa dìrọ̀ mọ́ obinrin olobinrin? Nítorí OLUWA rí gbogbo ohun tí eniyan ń ṣe, ó sì ń ṣàkíyèsí gbogbo ìrìn rẹ̀. Eniyan burúkú a máa jìn sinu ọ̀fìn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, a sì bọ́ sinu ìyọnu nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Yóo kú nítorí àìgba ìtọ́ni, yóo sì sọnù nítorí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀. Ọmọ mi, bí o bá ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ, tí o jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún àjèjì, tí o bá bọ́ sinu tàkúté tí o fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ dẹ fún ara rẹ, tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ sì ti kó bá ọ, o ti bọ́ sọ́wọ́ aládùúgbò rẹ. Nítorí náà báyìí ni kí o ṣe, ọmọ mi, kí o lè gba ara rẹ là: lọ bá a kíákíá, kí o sì bẹ̀ ẹ́. Má sùn, má sì tòògbé, gba ara rẹ sílẹ̀ bí àgbọ̀nrín tíí gba ara rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ ọdẹ, àní, bí ẹyẹ tíí ṣe, tíí fi í bọ́ lọ́wọ́ pẹyẹpẹyẹ. Ìwọ ọ̀lẹ, tọ èèrùn lọ, ṣàkíyèsí ìṣe rẹ̀, kí o sì kọ́gbọ́n. Ẹ̀dá tí kò ní olórí, tabi alabojuto, tabi aláṣẹ sibẹsibẹ, a máa tọ́jú oúnjẹ rẹ̀ ní àkókò ẹ̀ẹ̀rùn; a sì máa kó oúnjẹ jọ, ní àkókò ìkórè. O óo ti sùn pẹ́ tó, ìwọ ọ̀lẹ? Ìgbà wo ni o óo tají lójú oorun? Oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀, ìkáwọ́gbera díẹ̀ láti sinmi, yóo jẹ́ kí òṣì dé bá ọ, bí ọlọ́ṣà dé bá eniyan. Àìní yóo sì dé bá ọ bíi jagunjagun dé báni. Eniyan lásán, ìkà eniyan, a máa rìn káàkiri, a máa sọ̀rọ̀ àrékérekè, bí ó ti ń ṣẹ́jú, bẹ́ẹ̀ ni ó ń jansẹ̀ mọ́lẹ̀, tí ó sì ń fi ìka ṣe àpèjúwe. Ó ń fi inú burúkú pète ibi, ó sì ń fi ojoojumọ dá ìjà sílẹ̀, nítorí náà, ibi yóo dé bá a lójijì, yóo parun kíá láìsí àtúnṣe. Àwọn nǹkan mẹfa kan wà tí OLUWA kò fẹ́: wọ́n tilẹ̀ tó meje tí ó jẹ́ ohun ìríra fún un: Ìgbéraga, irọ́ pípa, ẹni tí ń déédé pa aláìṣẹ̀, ọkàn tí ń pète ìkà, ẹsẹ̀ tí ń sáré sí ibi, ẹlẹ́rìí èké tí ẹnu rẹ̀ kún fún irọ́, ati ẹni tí ń dá ìjà sílẹ̀ láàrin eniyan. Ọmọ mi, pa òfin baba rẹ mọ́, má sì ṣe kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ sílẹ̀. Fi wọ́n sọ́kàn nígbà gbogbo, kí o sì so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ. Nígbà tí o bá ń lọ, wọn yóo máa tọ́ ọ, bí o bá sùn, wọn yóo máa ṣọ́ ọ, bí o bá jí, wọn yóo máa bá ọ sọ̀rọ̀. Nítorí fìtílà ni òfin, ìmọ́lẹ̀ ni ẹ̀kọ́, ìbáwí sì jẹ́ ọ̀nà ìyè, láti pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ obinrin burúkú, ati lọ́wọ́ ẹnu alágbèrè obinrin tí ó dùn lọ́rọ̀. Má jẹ́ kí ẹwà rẹ̀ wù ọ́, má sì ṣe jẹ́ kí ó fi ìpéǹpéjú rẹ̀ mú ọ. Owó tí aṣẹ́wó yóo gbà kò ju owó burẹdi lọ, ṣugbọn gbogbo ẹ̀mí rẹ ni alágbèrè yóo fi ọgbọ́n gbà. Ǹjẹ́ ẹnìkan lè gbé iná ka àyà, kí aṣọ rẹ̀ má jó? Tabi eniyan lè rìn lórí ẹ̀yinná, kí iná má jó o lẹ́sẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ ẹni tí ó lọ bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀ rí, kò sí ẹni tí yóo ṣe bẹ́ẹ̀ tí yóo lọ láìjìyà. Ẹnìkan kì í kẹ́gàn olè tí ó bá jí oúnjẹ jẹ nítorí ebi. Sibẹsibẹ, bí ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́, yóo fi san ìlọ́po meje, ó lè jẹ́ pé gbogbo ohun ìní rẹ̀ ni yóo fi san án. Ẹni tí ó bá ṣe àgbèrè kò lọ́gbọ́n lórí, ẹni tí ó bá dán an wò, ara rẹ̀ ni ó ń parun. Ọgbẹ́ ati àbùkù ni yóo gbà, ìtìjú rẹ̀ kò sì ní kúrò lára rẹ̀ laelae. Nítorí owú jíjẹ a máa mú kí inú ọkọ ru, kò sì ní jẹ́ ṣàánú àlè bó bá di pé à ń gbẹ̀san. Kò ní gba owó ìtanràn, ọpọlọpọ ẹ̀bùn kò sì ní lè tù ú lójú. Ọmọ mi, pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kí o sì fi òfin mi sinu ọkàn rẹ. Pa òfin mi mọ́, kí o lè yè, pa ẹ̀kọ́ mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹyin ojú rẹ, wé wọn mọ́ ìka rẹ, kí o sì kọ wọ́n sí oókan àyà rẹ. Sọ fún ọgbọ́n pé, “Ìwọ ni arabinrin mi,” kí o sì pe ìmọ̀ ní ọ̀rẹ́ kòríkòsùn rẹ, kí wọ́n baà lè pa ọ́ mọ́, kúrò lọ́dọ̀ alágbèrè obinrin, ati kúrò lọ́wọ́ onírìnkurìn pẹlu ọ̀rọ̀ dídùn rẹ̀. Mo yọjú wo ìta, láti ojú fèrèsé ilé mi. Mo rí àwọn ọ̀dọ́ tí wọn kò ní ìrírí, mo ṣe akiyesi pé láàrin wọn, ọmọkunrin kan wà tí kò gbọ́n. Ó ń lọ ní òpópónà, lẹ́bàá kọ̀rọ̀ ilé alágbèrè obinrin náà, ní àṣáálẹ́, nígbà tí ọjọ́ ń pofírí, tí ilẹ̀ ti ń ṣú, tí òkùnkùn ti ń kùn. Obinrin kan lọ pàdé rẹ̀, ó wọ aṣọ aṣẹ́wó, ọkàn rẹ̀ kún fún ẹ̀tàn. Ó jẹ́ aláriwo ati onírìnkurìn obinrin, kì í gbélé rẹ̀. Bí ó ti ń rìn kiri lójú pópó, bẹ́ẹ̀ ni yóo máa lọ, tí yóo máa bọ̀ láàrin ọjà, yóo máa dọdẹ kiri ní gbogbo kọ̀rọ̀. Yóo bá dì mọ́ ọmọkunrin tí kò gbọ́n náà, yóo fi ẹnu kò ó lẹ́nu, yóo wí pẹlu ainitiju pé, “Mo ti rú ẹbọ alaafia, mo sì ti san ẹ̀jẹ́ mi lónìí. Nítorí náà, mo wá pàdé rẹ, mo fi ìlara wá ọ, mo sì rí ọ. Mo ti tẹ́ aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ aláràbarà ti ilẹ̀ Ijipti sórí ibùsùn mi. Mo tú turari olóòórùn dídùn ati òjíá, aloe ati sinamoni, sórí ibùsùn mi. Wá, jẹ́ kí á ṣeré ìfẹ́ títí ilẹ̀ yóo fi mọ́, jẹ́ kí á fi ìfẹ́ gbádùn ara wa. Ọkọ mi kò sí nílé, ó ti lọ sí ìrìn àjò, ọ̀nà rẹ̀ sì jìn. Ó mú owó pupọ lọ́wọ́, kò ní dé títí òṣùpá yóo fi di àrànmọ́jú.” Ó rọ̀ ọ́ pẹlu ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, ó fi ọ̀rọ̀ dídùn mú un. Lẹsẹkẹsẹ, ọmọkunrin náà bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀lé e, bíi mààlúù tí wọn ń fà lọ pa, tabi bí àgbọ̀nrín tí ó tẹsẹ̀ bọ tàkúté, títí tí ọfà fi wọ̀ ọ́ ninu bí ẹyẹ tí ń yára bọ́ sinu okùn, láì mọ̀ pé ó lè ṣe ikú pa òun. Nisinsinyii, ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ farabalẹ̀ gbọ́ nǹkan tí mò ń sọ. Ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín lọ sọ́dọ̀ irú obinrin bẹ́ẹ̀, ẹ má ṣèèṣì yà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ni àwọn tí ó ti sọ di ẹni ilẹ̀, ọpọlọpọ àwọn alágbára ni ó ti ṣe ikú pa. Ọ̀nà isà òkú tààrà ni ilé rẹ̀, ilé rẹ̀ ni ọ̀nà àbùjá sí ìparun. Ọgbọ́n ń pe eniyan, òye ń pariwo. Ó dúró ní ibi tí ó ga lẹ́bàá ọ̀nà, ati ní ojú ọ̀nà tóóró, ó ń kígbe lóhùn rara lẹ́nu ibodè àtiwọ ìlú, ó ń ké ní ẹnu ọ̀nà àbáwọlé pẹlu, ó ń wí pé: “Ẹ̀yin eniyan ni mò ń pè, gbogbo ọmọ eniyan ni mò ń ké sí. Ẹ̀yin òpè, ẹ kọ́ ọgbọ́n, ẹ̀yin òmùgọ̀, ẹ fetí sí òye. Ẹ tẹ́tí ẹ gbọ́, nítorí pé ọ̀rọ̀ pataki ni mo fẹ́ sọ. Ohun tí ó tọ́ ni n óo sì fi ẹnu mi sọ. Ọ̀rọ̀ òtítọ́ ni yóo ti ẹnu mi jáde, nítorí mo kórìíra ọ̀rọ̀ burúkú. Òdodo ni gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnu mi, kò sí ìtànjẹ tabi ọ̀rọ̀ àrékérekè ninu wọn. Gbogbo ọ̀rọ̀ náà tọ́ lójú ẹni tí ó mòye, wọn kò sì ní àbùkù lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n ní ìmọ̀. Gba ẹ̀kọ́ mi dípò fadaka, ati ìmọ̀ dípò ojúlówó wúrà, nítorí ọgbọ́n níye lórí ju ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye lọ, kò sí ohun tí o fẹ́, tí a lè fi wé e. Èmi, ọgbọ́n, òye ni mò ń bá gbélé, mo ṣe àwárí ìmọ̀ ati làákàyè. Ẹni tó bá bẹ̀rù OLUWA, yóo kórìíra ibi, mo kórìíra ìwà ìgbéraga, ọ̀nà ibi ati ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́. Èmi ni mo ní ìmọ̀ràn ati ọgbọ́n tí ó yè kooro, mo sì ní òye ati agbára. Nípasẹ̀ mi ni àwọn ọba fi ń ṣe ìjọba, tí àwọn alákòóso sì ń pàṣẹ òdodo. Nípasẹ̀ mi ni àwọn olórí ń ṣe àkóso, gbogbo àwọn ọlọ́lá sì ń ṣe àkóso ayé. Mo fẹ́ràn gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ràn mi, àwọn tí wọ́n bá fi tọkàntọkàn wá mi yóo sì rí mi. Ọrọ̀ ati iyì wà níkàáwọ́ mi, ọrọ̀ tíí tọ́jọ́, ati ibukun. Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ, àyọrísí mi sì dára ju ojúlówó fadaka lọ. Ọ̀nà òdodo ni èmi ń rìn, ojú ọ̀nà tí ó tọ́ ni mò ń tọ̀. Èmi a máa fún àwọn tí wọ́n fẹ́ mi ní ọrọ̀, n óo máa mú kí ìṣúra wọn kún. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ayé ni OLUWA ti dá mi, kí ó tó bẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ àrà rẹ̀. Láti ayébáyé ni a ti yàn mí, láti ìbẹ̀rẹ̀, kí á tó dá ayé rárá. Kí ibú omi tó wà ni mo ti wà, nígbà tí kò tíì sí àwọn orísun omi. Kí á tó dá àwọn òkè ńlá sí ààyè wọn, kí àwọn òkè kéékèèké tó wà, ni mo ti wà. Kí Ọlọrun tó dá ayé, ati pápá oko, kí ó tó dá erùpẹ̀ ilẹ̀. Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó dá ojú ọ̀run sí ààyè rẹ̀, tí ó ṣe àmì bìrìkìtì sórí ibú, ní ibi tí ó dàbí ẹni pé ilẹ̀ ati ọ̀run ti pàdé, nígbà tí ó ṣe awọsanma lọ́jọ̀, tí ó fi ìpìlẹ̀ orísun omi sọ ilẹ̀, nígbà tí ó pààlà sí ibi tí òkun gbọdọ̀ kọjá, kí omi má baà kọjá ààyè rẹ̀. Nígbà tí ó sàmì sí ibi tí ìpìlẹ̀ ayé wà, èmi ni oníṣẹ́ ọnà tí mo wà lọ́dọ̀ rẹ̀, Inú mi a máa dùn lojoojumọ, èmi a sì máa yọ̀ níwájú rẹ̀ nígbà gbogbo. Mo láyọ̀ ninu ayé tí àwọn ẹ̀dá alààyè ń gbé, inú mi sì ń dùn sí àwọn ọmọ eniyan. “Nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ fetí sí mi, ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà mi. Ẹ gbọ́ ìtọ́ni, kí ẹ sì kọ́gbọ́n, ẹ má sì ṣe àìnáání rẹ̀. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbọ́ tèmi, tí ó ń ṣọ́nà lojoojumọ ní ẹnu ọ̀nà àgbàlá mi, tí ó dúró sí ẹnu ọ̀nà ilé mi. Ẹni tí ó rí mi, rí ìyè, ó sì rí ojurere lọ́dọ̀ OLUWA, ṣugbọn ẹni tí kò bá rí mi, ó pa ara rẹ̀ lára, gbogbo àwọn tí wọ́n kórìíra mi, ikú ni wọ́n fẹ́ràn.” Ọgbọ́n ti kọ́lé, ó ti gbé àwọn òpó rẹ̀ mejeeje nàró. Ó ti pa ẹran rẹ̀, ó ti pọn ọtí waini rẹ̀, ó sì ti tẹ́ tabili rẹ̀ kalẹ̀. Ó ti rán àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ kí wọn lọ máa kígbe lórí àwọn òkè láàrin ìlú pé: “Ẹ yà síbí ẹ̀yin òpè!” Ó sọ fún ẹni tí kò lọ́gbọ́n pé, “Máa bọ̀, wá jẹ lára oúnjẹ mi, kí o sì mu ninu ọtí waini tí mo ti pò. Fi àìmọ̀kan sílẹ̀, kí o sì yè, kí o máa rin ọ̀nà làákàyè.” Ẹni tí ń tọ́ oníyẹ̀yẹ́ eniyan sọ́nà fẹ́ kan àbùkù, ẹni tí ń bá ìkà eniyan wí ń wá ìfarapa fún ara rẹ̀. Má ṣe bá oníyẹ̀yẹ́ eniyan wí, kí ó má baà kórìíra rẹ, bá ọlọ́gbọ́n wí, yóo sì fẹ́ràn rẹ. Kọ́ ọlọ́gbọ́n, yóo tún gbọ́n sí i, kọ́ olódodo, yóo sì tún ní ìmọ̀ kún ìmọ̀. Ìbẹ̀rù OLUWA ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n, ìmọ̀ Ẹni Mímọ́ sì ni làákàyè. Nípasẹ̀ mi ẹ̀mí rẹ yóo gùn. Ọpọlọpọ ọdún ni o óo sì lò lórí ilẹ̀ alààyè. Bí o bá gbọ́n, o óo jèrè ọgbọ́n rẹ, Bí o bá sì jẹ́ pẹ̀gànpẹ̀gàn, ìwọ nìkan ni o óo jèrè rẹ̀. Aláriwo ni obinrin tí kò gbọ́n, oníwọ̀ra ni, kò sì ní ìtìjú. Á máa jókòó lẹ́nu ọ̀nà ilé rẹ̀, á jókòó ní ibi tí ó ga láàrin ìlú. A máa kígbe pe àwọn tí ń kọjá lọ, àwọn tí ń bá tiwọn lọ jẹ́ẹ́jẹ́ wọn, pé, “Ẹni tí ó bá jẹ́ aláìmọ̀kan, kí ó máa bọ̀!” Ó sì wí fún àwọn òmùgọ̀ pé, “Omi tí eniyan bá jí mu a máa dùn, oúnjẹ tí a bá jí jẹ, oyinmọmọ ni.” Àwọn tí wọ́n bá yà sọ́dọ̀ rẹ̀ kò ní mọ̀ pé ikú wà ní ilé rẹ̀, ati pé inú isà òkú ni àwọn tí wọ́n bá wọ ilé rẹ̀ wọ̀. Àwọn òwe Solomoni nìwọ̀nyí: Ọlọ́gbọ́n ọmọ á máa mú kí inú baba rẹ̀ dùn, ṣugbọn òmùgọ̀ ọmọ a máa kó ìbànújẹ́ bá ìyá rẹ̀. Ọrọ̀ tí a kójọ lọ́nà èrú kò lérè, ṣugbọn òdodo a máa gba eniyan lọ́wọ́ ikú. OLUWA kì í jẹ́ kí ebi pa olódodo, ṣugbọn ó máa ń da ìfẹ́ ọkàn eniyan burúkú rú. Ìmẹ́lẹ́ máa ń fa òṣì, ṣugbọn ẹni tí ó bá tẹpá mọ́ṣẹ́ yóo di ọlọ́rọ̀. Ọlọ́gbọ́n ní ọmọ tí ó kórè ní àkókò ìkórè, ṣugbọn ọmọ tí ó bá ń sùn lákòókò ìkórè a máa kó ìtìjú báni. Ibukun wà lórí olódodo, ṣugbọn eniyan burúkú a máa fi ìwà ìkà sinu, a sì máa sọ̀rọ̀ rere jáde lẹ́nu. Ayọ̀ ni ìrántí olódodo, ṣugbọn orúkọ eniyan burúkú yóo di ohun ìgbàgbé. Ọlọ́gbọ́n a máa pa òfin mọ́, ṣugbọn òmùgọ̀ onísọkúsọ yóo di ẹni ìparun. Ẹni tí ó bá jẹ́ olóòótọ́ eniyan, yóo máa rìn láìfòyà, ṣugbọn àṣírí alágàbàgebè yóo tú. Ẹni tí bá ń ṣẹ́jú sí ni láti sọ̀rọ̀ èké, a máa dá ìjàngbọ̀n sílẹ̀, ṣugbọn ẹni tí bá ń báni wí ní gbangba, ń wá alaafia. Ẹnu olódodo dàbí orísun omi ìyè, ṣugbọn eniyan burúkú a máa fi ìwà ìkà sinu, a sì máa sọ̀rọ̀ rere jáde lẹ́nu. Ìkórìíra a máa rú ìjà sókè, ṣugbọn ìfẹ́ a máa fojú fo gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ dá. Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n níí máa ń jáde lẹ́nu ẹni tí ó ní òye, ṣugbọn kùmọ̀ ló yẹ ẹ̀yìn ẹni tí kò gbọ́n. Ọlọ́gbọ́n eniyan a máa wá ìmọ̀ kún ìmọ̀, ṣugbọn ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ máa ń fa ìparun mọ́ra. Ohun ìní ọlọ́rọ̀ ni ààbò rẹ̀, ṣugbọn àìní talaka ni yóo pa talaka run. Èrè àwọn olódodo a máa fa ìyè, ṣugbọn èrè àwọn eniyan burúkú a máa fà wọ́n sinu ẹ̀ṣẹ̀. Ẹni tí ó bá gba ìtọ́ni wà ní ọ̀nà ìyè, ṣugbọn ẹni tí ó bá kọ ìbáwí yóo ṣìnà. Ẹni tí ó di eniyan sinu jẹ́ ẹlẹ́tàn eniyan, ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́, òmùgọ̀ ni. Bí ọ̀rọ̀ bá ti pọ̀ jù, àṣìsọ a máa wọ̀ ọ́, ṣugbọn ẹni tí ó bá kó ẹnu ara rẹ̀ ní ìjánu, ọlọ́gbọ́n ni. Ọ̀rọ̀ ẹnu olódodo dàbí fadaka, ṣugbọn èrò ọkàn eniyan burúkú kò já mọ́ nǹkankan. Ọ̀rọ̀ ẹnu olódodo a máa ṣe ọpọlọpọ eniyan ní anfaani, ṣugbọn òmùgọ̀ eniyan a máa kú nítorí àìgbọ́n. Ibukun OLUWA ní ń mú ni í là, kì í sì í fi làálàá kún un. Ibi ṣíṣe a máa dùn mọ́ òmùgọ̀, ṣugbọn ìwà ọgbọ́n ni ayọ̀ fún ẹni tí ó mòye. Ohun tí eniyan burúkú ń bẹ̀rù ni yóo dé bá a, ohun tí olódodo ń fẹ́ ni yóo sì rí gbà. Nígbà tí ìjì líle bá ń jà, a gbá ẹni ibi lọ, ṣugbọn olódodo a fẹsẹ̀ múlẹ̀ títí lae. Bí ọtí kíkan ti rí sí eyín, ati bí èéfín ti rí sí ojú, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ rí sí ẹni tí ó bẹ̀ ẹ́ níṣẹ́. Ìbẹ̀rù OLUWA a máa mú kí ẹ̀mí eniyan gùn, ṣugbọn ìgbé ayé eniyan burúkú yóo kúrú. Ìrètí olódodo yóo yọrí sí ayọ̀, ṣugbọn ìrètí ẹni ibi yóo jásí òfo. OLUWA jẹ́ agbára fún àwọn tí ọ̀nà wọn tọ́, ṣugbọn ìparun ni fún àwọn oníṣẹ́ ibi. Gbọningbọnin ni olódodo yóo dúró, ṣugbọn ẹni ibi kò ní lè gbé ilẹ̀ náà. Ẹnu olódodo kún fún ọ̀rọ̀ ọgbọ́n, ṣugbọn ẹnu alaiṣootọ ni a pamọ́. Olódodo mọ ohun tí ó dára láti sọ, ṣugbọn ti eniyan burúkú kò ju ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn lọ. OLUWA kórìíra òṣùnwọ̀n èké, òṣùnwọ̀n tí ó péye ni inú rẹ̀ dùn sí. Bí ìgbéraga bá wọlé, àbùkù a tẹ̀lé e, ṣugbọn ọgbọ́n wà pẹlu àwọn onírẹ̀lẹ̀. Òtítọ́ inú àwọn olódodo a máa tọ́ wọn, ṣugbọn ìwà aiṣootọ àwọn ọ̀dàlẹ̀ níí pa wọ́n. Ọrọ̀ kò jámọ́ nǹkankan ní ọjọ́ ibinu, ṣugbọn òdodo a máa gbani sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú, Òdodo ẹni pípé a máa mú ọ̀nà rẹ̀ tọ́, ṣugbọn ẹni ibi ṣubú nípa ìwà ìkà rẹ̀. Ìwà òdodo àwọn olóòótọ́ yóo gbà wọ́n, ṣugbọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀dàlẹ̀ yóo dè wọ́n nígbèkùn. Nígbà tí àwọn eniyan burúkú bá kú, ìrètí wọn yóo di asán, bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn tí kò mọ Ọlọrun yóo di òfo. OLUWA a máa gba olódodo lọ́wọ́ ìyọnu, ṣugbọn ẹni ibi a bọ́ sinu wahala. Ẹni tí kò mọ Ọlọrun a máa fi ẹnu ba ti aládùúgbò rẹ̀ jẹ́, ṣugbọn nípa ìmọ̀ a máa gba olódodo sílẹ̀. Nígbà tí nǹkan bá ń dára fún olódodo, gbogbo ará ìlú a máa yọ̀, nígbà tí eniyan burúkú bá kú, gbogbo ará ìlú a sì hó ìhó ayọ̀. Ìre tí olódodo bá sú fún ìlú a máa gbé orúkọ ìlú ga, ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn eniyan burúkú a máa run ìlú. Ẹni tí ó tẹmbẹlu aládùúgbò rẹ̀ kò gbọ́n, ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa pa ẹnu mọ́. Olófòófó a máa tú àṣírí, ṣugbọn ẹni tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé a máa pa àṣírí mọ́. Níbi tí kò bá ti sí ìtọ́ni, orílẹ̀-èdè a máa ṣubú, ṣugbọn ẹni tí ó bá ní ọpọlọpọ olùdámọ̀ràn yóo máa gbé ní àìléwu. Ẹni tí ó bá ṣe onídùúró fún àlejò yóo rí ìyọnu, ṣugbọn ẹni tí ó bá kọ̀ tí kò ṣe onídùúró yóo wà láìléwu. Obinrin onínúrere gbayì, ṣugbọn ọrọ̀ nìkan ni ìkà yóo ní. Ẹni tí ó ṣoore ṣe é fún ara rẹ̀, ẹni tí ó sì ń ṣìkà ó ń ṣe é fún ara rẹ̀. Owó ọ̀yà èké ni eniyan burúkú óo gbà, ṣugbọn ẹni tí ó bá hùwà òdodo yóo gba èrè òtítọ́. Ẹni tí ó dúró ṣinṣin lórí òdodo yóo yè, ṣugbọn ẹni tí ó bá ń lépa ibi yóo kú. Ẹni ìríra ni àwọn alágàbàgebè lójú OLUWA, ṣugbọn àwọn tí ọ̀nà wọn mọ́ ni ìdùnnú fún un. Dájúdájú ẹni ibi kò ní lọ láìjìyà, ṣugbọn a óo gba àwọn olódodo là. Bí òrùka wúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀ ni obinrin tí ó lẹ́wà tí kò ní làákàyè. Ìfẹ́ ọkàn olódodo a máa yọrí sí rere, ṣugbọn ìrètí eniyan burúkú a máa já sí ibinu. Ẹnìkan wà tíí máa ṣe ìtọrẹ àánú káàkiri, sibẹsibẹ àníkún ni ó ń ní, ẹnìkan sì wà tí ó háwọ́, sibẹsibẹ aláìní ni. Ẹni tí ó bá lawọ́ yóo máa ní àníkún, ẹni tí ó bá jẹ́ kí ọkàn ẹlòmíràn balẹ̀, ọkàn tirẹ̀ náà yóo balẹ̀. Ẹni tí ó bá ń kó oúnjẹ pamọ́, yóo gba ègún sórí, ṣugbọn ẹni tí ó bá ń ta oúnjẹ, yóo rí ibukun gbà. Ẹni tí ó bá ń wá ire, yóo rí ojurere, ṣugbọn ẹni tí ó bá ń wá ibi, ibi yóo bá a. Ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ yóo rẹ̀ dànù bí òdòdó, ṣugbọn olódodo yóo rú bí ewé tútù. Ẹni tí ó bá mú ìyọnu dé bá ìdílé rẹ̀ yóo jogún òfo, òmùgọ̀ ni yóo sì máa ṣe iranṣẹ ọlọ́gbọ́n. Èso olódodo ni igi ìyè, ṣugbọn ìwà aibikita fún òfin a máa paniyan. Bí a óo bá san ẹ̀san fún olódodo láyé, mélòó-mélòó ni ti eniyan burúkú ati ẹlẹ́ṣẹ̀. Ẹni tí ó fẹ́ ìtọ́sọ́nà, ó fẹ́ ìmọ̀, ṣugbọn ẹni tí ó kórìíra ìbáwí òmùgọ̀ ni. Eniyan rere a máa ní ojurere lọ́dọ̀ OLUWA, ṣugbọn ẹni tí ń pète ìkà ni yóo dá lẹ́bi. Kò sí ẹni tí ó lè ti ipa ìwà ìkà fi ìdí múlẹ̀, ṣugbọn gbòǹgbò olódodo kò ní fà tu. Obinrin oníwàrere ni adé orí ọkọ rẹ̀, ṣugbọn obinrin tí ń dójúti ọkọ dàbí ọyún inú egungun. Èrò ọkàn olódodo dára, ṣugbọn ẹ̀tàn ni ìmọ̀ràn àwọn eniyan burúkú. Ọ̀rọ̀ àwọn eniyan burúkú dàbí ẹni tí ó lúgọ láti pa eniyan, ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹnu olódodo a máa gbani là. A bi àwọn eniyan burúkú lulẹ̀, wọ́n sì parun, ṣugbọn ìdílé olódodo yóo dúró gbọningbọnin. À máa ń yin eniyan gẹ́gẹ́ bí ó bá ṣe gbọ́n tó, ṣugbọn ọlọ́kàn àgàbàgebè yóo di ẹni ẹ̀gàn. Mẹ̀kúnnù tí ó ní iṣẹ́, tí ó tún gba ọmọ-ọ̀dọ̀ ó sàn ju ẹni tí ó ń ṣe bí eniyan pataki, ṣugbọn tí kò rí oúnjẹ jẹ lọ. Olódodo a máa ka ẹ̀mí ẹran ọ̀sìn rẹ̀ sí, ṣugbọn eniyan burúkú rorò sí tirẹ̀. Ẹni tí ó bá ń dáko yóo ní ọ̀pọ̀ oúnjẹ, ṣugbọn ẹni tí ó bá ń lo àkókò rẹ̀ lórí ohun tí kò lérè, kò lọ́gbọ́n lórí. Ilé ìṣọ́ àwọn eniyan burúkú yóo di òkítì àlàpà, ṣugbọn gbòǹgbò eniyan rere a máa fìdí múlẹ̀ sí i. Ọ̀rọ̀ ẹnu eniyan burúkú a máa mú un bíi tàkúté, ṣugbọn olódodo a máa bọ́ ninu ìyọnu. Ọ̀rọ̀ ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa mú ìtẹ́lọ́rùn bá a, a sì máa jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Ọ̀nà òmùgọ̀ níí dára lójú tirẹ̀, ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa fetí sí ìmọ̀ràn. Bí inú bá ń bí òmùgọ̀, kíá ni gbogbo eniyan yóo mọ̀, ṣugbọn ọlọ́gbọ́n kìí ka ọ̀rọ̀ àbùkù sí. Ẹni tí ó bá ń sọ òtítọ́ a máa jẹ́rìí òdodo, ṣugbọn irọ́ ni ẹlẹ́rìí èké máa ń pa. Ẹni tí í bá máa ń sọ̀rọ̀ jàbùjàbù láìronú, ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí kí á fi idà gún eniyan, ṣugbọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹni wo ọgbẹ́ sàn. Ọ̀rọ̀ òtítọ́ yóo máa wà títí ayé ṣugbọn irọ́, fún ìgbà díẹ̀ ni. Ẹ̀tàn ń bẹ lọ́kàn àwọn tí ń pète ibi, ṣugbọn àwọn tí ń gbèrò rere ní ayọ̀. Nǹkan burúkú kò ní ṣẹlẹ̀ sí olódodo, ṣugbọn eniyan burúkú yóo kún fún ìyọnu. OLUWA kórìíra ẹni tí ń parọ́, ṣugbọn inú rẹ̀ dùn sí olóòótọ́. Ọlọ́gbọ́n a máa fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́, ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ a máa kéde agọ̀ wọn. Ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ ni yóo máa jẹ́ olórí, ṣugbọn ọ̀lẹ ni a óo máa mú ṣiṣẹ́ tipátipá. Ọ̀pọ̀ ìpayà máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá eniyan, ṣugbọn ọ̀rọ̀ rere a máa mú inú eniyan dùn. Olódodo a máa yipada kúrò ninu ibi, ṣugbọn ìwà ẹni ibi a máa mú un ṣìnà. Ọwọ́ ọ̀lẹ kò lè tẹ ohun tí ó ń lé, ṣugbọn ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ yóo ní ọpọlọpọ ọrọ̀. Ní ọ̀nà òdodo ni ìyè wà, kò sí ikú ní ojú ọ̀nà rẹ̀. Ọlọ́gbọ́n ọmọ a máa gba ẹ̀kọ́ baba rẹ̀, ṣugbọn ẹlẹ́yà kì í gbọ́ ìbáwí. Eniyan rere a máa rí ire nítorí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀, ṣugbọn ohun tí àwọn ẹlẹ́tàn ń fẹ́ ni ìwà jàgídíjàgan. Ẹni tí ó ń ṣọ́ ẹnu rẹ̀, ẹ̀mí ara rẹ̀ ni ó ń ṣọ́, ẹni tí ń sọ̀rọ̀ àsọjù yóo parun. Ọkàn ọ̀lẹ ń fẹ́ nǹkan, ṣugbọn kò ní rí i, ṣugbọn ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ yóo ní ọpọlọpọ nǹkan. Olóòótọ́ a máa kórìíra èké, ṣugbọn eniyan burúkú a máa hùwà ìtìjú ati àbùkù. Òdodo a máa dáàbò bo ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ bá tọ́, ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ a máa bi eniyan burúkú ṣubú. Ẹnìkan ń ṣe bí ọlọ́rọ̀, bẹ́ẹ̀ kò ní nǹkankan, níbẹ̀ ni ẹlòmíràn ń ṣe bíi talaka, ṣugbọn tí ó ní ọpọlọpọ ọrọ̀. Ọlọ́rọ̀ a máa fi ohun ìní rẹ̀ ra ẹ̀mí rẹ̀ pada, ṣugbọn talaka kì í tilẹ̀ gbọ́ ìbáwí. Ìmọ́lẹ̀ olódodo a máa fi ayọ̀ tàn, ṣugbọn fìtílà eniyan burúkú yóo kú. Ìjà ni ìgbéraga máa ń fà, ṣugbọn àwọn tí wọ́n bá gba ìmọ̀ràn yóo ní ọgbọ́n. Ọrọ̀ tí a fi ìkánjú kójọ kì í pẹ́ dínkù, ṣugbọn ẹni tí ó bá fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kó ọrọ̀ jọ yóo máa ní àníkún. Bí ìrètí bá pẹ́ jù, a máa kó àárẹ̀ bá ọkàn, ṣugbọn kí á tètè rí ohun tí à ń fẹ́ a máa mú ara yá gágá. Ẹni tí ó kẹ́gàn ìmọ̀ràn yóo parun, ṣugbọn ẹni tí ó bá bẹ̀rù òfin yóo jèrè rẹ̀. Ìtọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè a máa yọni ninu tàkúté ikú. Ẹni tí ó ní òye yóo rí ojurere, ṣugbọn ọ̀nà àwọn tí kò ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ni ìparun wọn. Olóye eniyan a máa fi ìmọ̀ ṣe ohun gbogbo, ṣugbọn òmùgọ̀ a máa fi agọ̀ rẹ̀ yangàn. Iranṣẹ burúkú a máa kó àwọn eniyan sinu wahala, ṣugbọn ikọ̀ tí ó bá jẹ́ olóòótọ́ a máa mú ìrẹ́pọ̀ wá. Òṣì ati àbùkù ni yóo bá ẹni tí ó kọ ìmọ̀ràn, ṣugbọn ẹni tó bá gba ìbáwí yóo gba iyì. Bí èrò ọkàn ẹni bá ṣẹ, a máa fúnni láyọ̀, ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ kórìíra ati kọ ibi sílẹ̀. Bí eniyan bá ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóo gbọ́n, ṣugbọn ẹni tí ó bá ń bá òmùgọ̀ kẹ́gbẹ́ yóo ṣìnà. Àjálù kì í dẹ̀yìn lẹ́yìn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn olódodo yóo máa rí ire. Eniyan rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, ṣugbọn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń kó ọrọ̀ jọ fún àwọn olóòótọ́. Oko tí talaka dá lè mú ọpọlọpọ oúnjẹ jáde, ṣugbọn àwọn alaiṣootọ níí kó gbogbo rẹ̀ lọ. Ẹni tí kì í bá na ọmọ rẹ̀ kò fẹ́ràn rẹ̀, ṣugbọn ẹni tí ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ yóo máa bá a wí. Olódodo a máa jẹ àjẹtẹ́rùn, ṣugbọn eniyan burúkú kì í yó. Ọlọ́gbọ́n obinrin a máa kọ́ ilé rẹ̀, ṣugbọn òmùgọ̀ a máa fi ọwọ́ ara rẹ̀ tú tirẹ̀ palẹ̀. Ẹni tí ń rìn pẹlu òótọ́ inú yóo bẹ̀rù OLUWA, ṣugbọn ẹni tí ń rin ìrìn ségesège yóo kẹ́gàn rẹ̀. Ọ̀rọ̀ ẹnu òmùgọ̀ dàbí pàṣán ní ẹ̀yìn ara rẹ̀, ṣugbọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n a máa dáàbò bò ó. Níbi tí kò bá sí mààlúù tí ń tu ilẹ̀, kò lè sí oúnjẹ, ṣugbọn agbára ọpọlọpọ mààlúù níí mú ọpọlọpọ ìkórè wá. Ẹlẹ́rìí òtítọ́ kì í parọ́, ṣugbọn irọ́ ṣá ni ti ẹlẹ́rìí èké. Pẹ̀gànpẹ̀gàn a máa wá ọgbọ́n, sibẹ kò ní rí i, ṣugbọn ati ní ìmọ̀ kò ṣòro fún ẹni tí ó ní òye. Yẹra fún òmùgọ̀, nítorí o kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n lẹ́nu rẹ̀. Ohun tí ó jẹ́ ọgbọ́n fún ọlọ́gbọ́n ni pé kí ó kíyèsí ọ̀nà ara rẹ̀, ṣugbọn àìmòye àwọn òmùgọ̀ kún fún ìtànjẹ. Àwọn òmùgọ̀ a máa fi ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ṣe àwàdà, ṣugbọn àwọn olódodo a máa rí ojurere. Kálukú ló mọ ìbànújẹ́ ọkàn ara rẹ̀, kò sì sí àjèjì tí ń báni pín ninu ayọ̀. Ìdílé ẹni ibi yóo parun, ṣugbọn ilé olódodo yóo máa gbèrú títí lae. Ọ̀nà kan wà tí ó dàbí ẹni pé ó tọ́ lójú eniyan, ṣugbọn òpin rẹ̀, ikú ni. Eniyan lè máa rẹ́rìn-ín, kí inú rẹ̀ má dùn, ìbànújẹ́ sì le gbẹ̀yìn ayọ̀. Alágàbàgebè yóo jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, ẹni rere yóo sì jèrè ìwà rere rẹ̀. Òpè eniyan a máa gba ohun gbogbo gbọ́, ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa kíyèsí ibi tí ó ń lọ. Ọlọ́gbọ́n a máa ṣọ́ra, a sì máa sá fún ibi, ṣugbọn òmùgọ̀ kì í rọra ṣe, kì í sì í bìkítà. Onínúfùfù a máa hùwà òmùgọ̀, ṣugbọn onílàákàyè a máa ní sùúrù. Àwọn òpè a máa jogún àìgbọ́n, ṣugbọn àwọn ọlọ́gbọ́n a máa dé adé ìmọ̀. Àwọn ẹni ibi yóo tẹríba fún àwọn ẹni rere, àwọn eniyan burúkú yóo sì tẹríba lẹ́nu ọ̀nà àwọn olódodo. Àwọn aládùúgbò talaka pàápàá kórìíra rẹ̀, ṣugbọn ọlọ́rọ̀ a máa ní ọpọlọpọ ọ̀rẹ́. Ẹni tí ó kẹ́gàn aládùúgbò rẹ̀ dẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn ayọ̀ ń bẹ fun ẹni tí ó bá ṣàánú talaka. Àwọn tí wọn ń pète ibi ti ṣìnà, ṣugbọn àwọn tí wọn ń gbèrò ire yóo rí ojurere ati òtítọ́. Kò sí iṣẹ́ kan tí kò lérè, ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹnu lásán láìsí iṣẹ́, a máa sọ eniyan di aláìní. Ọgbọ́n ni adé àwọn ọlọ́gbọ́n, ṣugbọn ìwà aláìgbọ́n jẹ́ yẹ̀yẹ́ àwọn òmùgọ̀. Ẹlẹ́rìí tòótọ́ a máa gba ẹ̀mí là, ṣugbọn ọ̀dàlẹ̀ ni òpùrọ́. Ninu ìbẹ̀rù OLUWA ni igbẹkẹle tí ó dájú wà, níbẹ̀ ni ààbò wà fún àwọn ọmọ ẹni. Ìbẹ̀rù OLUWA ni orísun ìyè, òun níí mú ká yẹra fún tàkúté ikú. Ọ̀pọ̀ eniyan ni ògo ọba, olórí tí kò bá ní eniyan yóo parun. Ẹni tí kì í báá yára bínú lóye lọpọlọpọ, ṣugbọn onínúfùfù ń fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn. Ìbàlẹ̀ ọkàn a máa mú kí ara dá ṣáṣá, ṣugbọn ìlara a máa dá egbò sinu eegun. Ẹni tí ó bá ni talaka lára àbùkù Ẹlẹ́dàá rẹ̀ ni ó ń ta, ṣugbọn ẹni tí ó ṣàánú fún àwọn aláìní ń bu ọlá fún Ẹlẹ́dàá rẹ̀. Eniyan burúkú ṣubú nítorí ìwà ibi rẹ̀, ṣugbọn olódodo rí ààbò nípasẹ̀ òtítọ́ inú rẹ̀. Ọgbọ́n kún inú ẹni tí ó mòye, ṣugbọn kò sí ohun tí ó jọ ọgbọ́n lọ́kàn òmùgọ̀. Òdodo ní ń gbé orílẹ̀-èdè lékè, ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ẹ̀gàn fún orílẹ̀-èdè. Iranṣẹ tí ó bá hùwà ọlọ́gbọ́n a máa rí ojurere ọba, ṣugbọn inú a máa bí ọba sí iranṣẹ tí ó bá hùwà ìtìjú. Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ a máa mú kí ibinu rọlẹ̀, ṣugbọn ọ̀rọ̀ líle níí ru ibinu sókè. Lẹ́nu ọlọ́gbọ́n ni ọ̀rọ̀ ìmọ̀ ti ń jáde, ṣugbọn òmùgọ̀ a máa sọ̀rọ̀ agọ̀. Ojú OLUWA wà níbi gbogbo, ó ń ṣọ́ àwọn eniyan burúkú ati àwọn eniyan rere. Ọ̀rọ̀ tí a fi pẹ̀lẹ́ sọ dàbí igi ìyè, ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn a máa bani lọ́kàn jẹ́. Òmùgọ̀ ọmọ á kẹ́gàn ìtọ́sọ́nà baba rẹ̀, ṣugbọn ọmọ tí ó gbọ́ ìkìlọ̀, ọlọ́gbọ́n ni. Ilé olódodo kún fún ọpọlọpọ ìṣúra, ṣugbọn kìkì ìdààmú ni àkójọ èrè eniyan burúkú. Ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa tan ìmọ̀ kálẹ̀, ṣugbọn ti òmùgọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀. Ohun ìríra ni ẹbọ eniyan burúkú lójú OLUWA, ṣugbọn adura olódodo jẹ́ ìdùnnú rẹ̀. OLUWA kórìíra ìwà àwọn eniyan burúkú, ṣugbọn ó fẹ́ràn àwọn tí ń hùwà òdodo. Ìbáwí pupọ ń bẹ fún ẹni tí ó yapa kúrò ní ọ̀nà rere, ẹni tí ó bá kórìíra ìbáwí yóo kú. Isà òkú ati ìparun kò pamọ́ lójú OLUWA, mélòó-mélòó ni ọkàn eniyan. Inú pẹ̀gànpẹ̀gàn kì í dùn sí ìbáwí, kì í bèèrè ìmọ̀ràn lọ́wọ́ ọlọ́gbọ́n. Inú dídùn a máa múni dárayá, ṣugbọn ìbànújẹ́ a máa mú kí ojú eniyan rẹ̀wẹ̀sì. Ẹni tí ó ní òye a máa wá ìmọ̀, ṣugbọn agọ̀ ni oúnjẹ òmùgọ̀. Gbogbo ọjọ́ ayé ẹni tí a ni lára kún fún ìpọ́njú, ṣugbọn ojoojumọ ni ọdún fún ẹni tí inú rẹ̀ dùn. Ó sàn kí á jẹ́ talaka, kí á sì ní ìbẹ̀rù OLUWA, ju kí á jẹ́ ọlọ́rọ̀, kí á sì kún fún ìyọnu lọ. Ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ pẹlu ìfẹ́, sàn ju ẹran mààlúù tòun ti ìkórìíra lọ. Onínúfùfù a máa rú ìjà sókè, ṣugbọn onínútútù a máa pẹ̀tù sí ibinu. Ẹ̀gún kún bo ọ̀nà ọ̀lẹ, ṣugbọn ọ̀nà olódodo dàbí òpópó tí ń dán. Ọlọ́gbọ́n ọmọ a máa mú inú baba rẹ̀ dùn, ṣugbọn òmùgọ̀ ọmọ níí kẹ́gàn ìyá rẹ̀. Ayọ̀ ni ìwà òmùgọ̀ jẹ́ fún aláìgbọ́n, ṣugbọn ẹni tí ó ní òye a máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Àìsí ìmọ̀ràn a máa mú kí ètò dàrú, ṣugbọn ọpọlọpọ ìmọ̀ràn a máa mú kí ó yọrí sí rere. Ìdáhùn kíkún a máa fúnni láyọ̀, kí ọ̀rọ̀ bọ́ sí àsìkò dára lọpọlọpọ! Ọ̀nà ọlọ́gbọ́n lọ tààrà sinu ìyè, kí ó má baà bọ́ sinu isà òkú. OLUWA a máa wó ilé agbéraga, ṣugbọn ó ṣe àmójútó ààlà opó. Ohun ìríra ni èrò ọkàn ẹni ibi lójú OLUWA, ṣugbọn ọrọ̀ àwọn ẹni mímọ́ jẹ́ dídùn inú rẹ̀. Àwọn tí ń ṣojúkòkòrò èrè àìtọ́ ń kó ìyọnu bá ilé wọn, ṣugbọn àwọn tí wọn kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yóo yè. Olódodo a máa ronú kí ó tó fèsì ọ̀rọ̀, ṣugbọn ọ̀rọ̀ burúkú níí máa jáde lẹ́nu àwọn eniyan burúkú. OLUWA jìnnà sí eniyan burúkú, ṣugbọn a máa gbọ́ adura olódodo. Ọ̀yàyà a máa mú inú dùn, ìròyìn ayọ̀ a sì máa mú ara yá. Ẹni tó gbọ́ ìbáwí rere yóo wà láàrin àwọn ọlọ́gbọ́n. Ẹni tí kò náání ìbáwí tàbùkù ara rẹ̀, ṣugbọn ẹni tí ó bá gba ìmọ̀ràn yóo ní òye. Ìbẹ̀rù OLUWA níí kọ́ni lọ́gbọ́n, ìwà ìrẹ̀lẹ̀ níí ṣáájú iyì. Èrò ọkàn ni ti eniyan ṣugbọn OLUWA ló ni ìdáhùn. Gbogbo ọ̀nà eniyan ni ó mọ́ lójú ara rẹ̀, ṣugbọn OLUWA ló rí ọkàn. Fi gbogbo àdáwọ́lé rẹ lé OLUWA lọ́wọ́, èrò ọkàn rẹ yóo sì yọrí sí rere. OLUWA a máa jẹ́ kí ohun gbogbo yọrí sí bí ó bá ti fẹ́, ó dá eniyan burúkú fún ọjọ́ ìyọnu. OLUWA kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ agbéraga, dájúdájú kò ní lọ láìjìyà. Àánú ati òtítọ́ a máa ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀, ìbẹ̀rù OLUWA a sì máa mú ibi kúrò. Bí ọ̀nà eniyan bá tẹ́ OLUWA lọ́rùn, a máa mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ pàápàá bá a gbé pẹlu alaafia. Ìwọ̀nba ọrọ̀ pẹlu òdodo, sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ tí a kójọ lọ́nà èrú lọ. Eniyan lè jókòó kí ó ṣètò ìgbésẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn OLUWA níí tọ́ ìṣísẹ̀ ẹni. Pẹlu ìmísí Ọlọrun ni ọba fi ń sọ̀rọ̀, ìdájọ́ aiṣododo kò gbọdọ̀ ti ẹnu rẹ̀ jáde. Ti OLUWA ni òṣùnwọ̀n pípé, iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo ohun tí à ń wọ̀n. Àwọn ọba kórìíra ibi ṣíṣe, nítorí nípa òdodo ni a fìdí ìjọba múlẹ̀. Inú ọba a máa dùn sí olódodo, ọba sì máa ń fẹ́ràn àwọn tí ń sọ òtítọ́. Iranṣẹ ikú ni ibinu ọba, ọlọ́gbọ́n eniyan níí tù ú lójú. Ìyè wà ninu ojurere ọba, ojurere rẹ̀ sì dàbí ṣíṣú òjò ní àkókò òjò àkọ́rọ̀. Ó sàn kí eniyan ní òye ju kí ó ní wúrà lọ, ó sì sàn kí eniyan yan ìmọ̀ ju kí ó yan fadaka lọ. Olóòótọ́ kì í tọ ọ̀nà ibi, ẹni tí ń ṣọ́ra, ẹ̀mí ara rẹ̀ ni ó ń pamọ́. Ìgbéraga ní ń ṣáájú ìparun, agídí ní ń ṣáájú ìṣubú. Ó sàn kí eniyan jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ pẹlu àwọn talaka ju kí ó bá agbéraga pín ìkógun lọ. Yóo dára fún ẹni tí ó bá ń gbọ́ràn, ẹni tí ó bá sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA yóo ní ayọ̀. Àwọn tí wọ́n gbọ́n ni à ń pè ní amòye, ọ̀rọ̀ tí ó tuni lára a máa yíni lọ́kàn pada. Orísun ìyè ni ọgbọ́n jẹ́ fún àwọn tí wọn ní i, agọ̀ sì jẹ́ ìjìyà fún àwọn òmùgọ̀. Ọgbọ́n inú níí mú kí ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n tọ̀nà, ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ a sì máa yíni lọ́kàn pada. Ọ̀rọ̀ tí ó tuni lára dàbí afárá oyin, a máa mú inú ẹni dùn, a sì máa mú ara ẹni yá. Ọ̀nà kan wà tí ó tọ́ lójú eniyan, ṣugbọn òpin rẹ̀, ikú ni. Ebi níí mú kí òṣìṣẹ́ múra síṣẹ́, ohun tí a óo jẹ ní ń lé ni kiri. Eniyan lásán a máa pète ibi, ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ dàbí iná tí ń jóni. Ṣòkèṣodò a máa dá ìjà sílẹ̀, ọ̀rọ̀ àhesọ a máa tú ọ̀rẹ́ kòríkòsùn. Ìkà eniyan tan aládùúgbò rẹ̀, ó darí rẹ̀ lọ sọ́nà tí kò tọ́. Ẹni tí ó bá ń ṣẹ́jú sí ni, ète ibi ló fẹ́ pa, ẹni tí ó bá ń fúnnu pọ̀ sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ burúkú ni yóo sọ jáde. Adé ògo ni ewú orí, nípa ìgbé ayé òdodo ni a fi lè ní i. Ẹni tí kì í tètè bínú sàn ju alágbára lọ, ẹni tí ń kó ara rẹ̀ níjàánu sàn ju ẹni tí ó jagun gba odidi ìlú lọ. À máa ṣẹ́ gègé kí á lè mọ ìdí ọ̀ràn, ṣugbọn OLUWA nìkan ló lè pinnu ohunkohun. Kí á fi alaafia jẹun, láìsí ọbẹ̀, ó sàn ju kí á máa fi ẹran jẹun pẹlu ìyọnu lọ. Ẹrú tí ó bá mọ ìwà hù, yóo di ọ̀gá lórí ọmọ tí ń hùwà ìbàjẹ́, yóo sì jókòó pín ninu ogún bí ẹni pé ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ni. Iná ni a fi ń dán fadaka ati wúrà wò, ṣugbọn OLUWA ní ń dán ọkàn wò. Aṣebi a máa tẹ́tí sí ẹni ibi, òpùrọ́ a sì máa fetí sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ìkà. Ẹni tí ń fi talaka ṣẹ̀sín, ẹlẹ́dàá talaka ní ń tàbùkù, ẹni tí inú rẹ̀ dùn sí wahala ẹni ẹlẹ́ni kò ní lọ láìjìyà. Ọmọ ọmọ ni adé arúgbó, òbí sì ni ògo àwọn ọmọ. Ọ̀rọ̀ rere ṣe àjèjì sí ẹnu òmùgọ̀, bẹ́ẹ̀ ni irọ́ pípa kò yẹ àwọn olórí. Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ dàbí òògùn ajẹ́-bí-idán lójú ẹni tí ń fúnni, ibi gbogbo tí olúwarẹ̀ bá lọ ni ó ti ń ṣe àṣeyege. Ẹni tí ń dárí ji ni ń wá ìfẹ́, ẹni tí ń tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ a máa ya ọ̀rẹ́ nípá. Ìbáwí a máa dun ọlọ́gbọ́n ju kí wọ́n nà òmùgọ̀ ní ọgọrun-un pàṣán lọ. Ọ̀tẹ̀ ṣá ni ti eniyan burúkú ní gbogbo ìgbà, ìkà òjíṣẹ́ ni a óo sì rán sí i. Ó sàn kí eniyan pàdé ẹranko beari tí a kó lọ́mọ, ju kí ó pàdé òmùgọ̀ ninu agọ̀ rẹ̀ lọ. Ẹni tí ó fibi san oore, ibi kò ní kúrò ninu ilé rẹ̀ lae. Ìbẹ̀rẹ̀ ìjà dàbí kí eniyan ya odò tí wọn sé, dá a dúró kí ó tó di ńlá. Ẹni tí ń gbé àre fún ẹlẹ́bi ati ẹni tí ń gbé ẹ̀bi fún aláre, OLUWA kórìíra ekinni-keji wọn. Owó kò wúlò lọ́wọ́ òmùgọ̀ pé kí ó fi ra ọgbọ́n, nígbà tí kò ní òye? Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo, ṣugbọn a bí arakunrin láti dúró tini ní ìgbà ìpọ́njú. Ẹni tí kò bá gbọ́n níí jẹ́jẹ̀ẹ́, láti ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ̀. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn ìjà fẹ́ràn ẹ̀ṣẹ̀, ẹni tí ó bá fẹ́ràn kí á máa fi owó ṣe àṣehàn ń wá ìparun. Ẹni tí ó ní ọkàn ẹ̀tàn kò ní ṣe àṣeyege, ẹlẹ́nu meji yóo bọ́ sinu ìyọnu. Ìbànújẹ́ ni kí eniyan bí ọmọ tí kò gbọ́n, kò sí ayọ̀ fún baba òmùgọ̀. Ọ̀yàyà jẹ́ òògùn tí ó dára fún ara, ṣugbọn ìbànújẹ́ a máa mú kí eniyan rù. Eniyan burúkú a máa gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ níkọ̀kọ̀, láti yí ìdájọ́ po. Ẹni tí ó ní òye a máa tẹjúmọ́ ọgbọ́n, ṣugbọn ojú òmùgọ̀ kò gbé ibìkan, ó ń wo òpin ilẹ̀ ayé. Òmùgọ̀ ọmọ jẹ́ ìbànújẹ́ baba rẹ̀, ati ọgbẹ́ ọkàn fún ìyá tí ó bí i. Kò tọ̀nà láti fi ipá mú aláìṣẹ̀ san owó ìtanràn, nǹkan burúkú ni kí á na gbajúmọ̀ tí kò rú òfin. Ẹni tí ó bá ní ìmọ̀ a máa kó ahọ́n rẹ̀ ní ìjánu, ẹni tí ó bá jẹ́ olóye eniyan a máa ṣe jẹ́ẹ́. A máa ka òmùgọ̀ pàápàá kún ọlọ́gbọ́n, bí ó bá pa ẹnu rẹ̀ mọ́, olóye ni àwọn eniyan yóo pè é, bí ó bá panu mọ́ tí kò sọ̀rọ̀. Onímọ-tara-ẹni-nìkan ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀, láti tako ìdájọ́ òtítọ́. Òmùgọ̀ kò ní inú dídùn sí ìmọ̀, àfi kí ó ṣá máa sọ èrò ọkàn rẹ̀. Nígbà tí ìwà burúkú bá dé, ẹ̀gàn yóo dé, bí àbùkù bá wọlé ìtìjú yóo tẹ̀lé e. Ọ̀rọ̀ ẹnu eniyan dàbí odò jíjìn, orísun ọgbọ́n dàbí omi odò tí ń tú jáde. Kò dára kí á ṣe ojuṣaaju sí eniyan burúkú, tabi kí á dá olódodo ní ẹjọ́ ẹ̀bi. Ẹnu òmùgọ̀ a máa dá ìjà sílẹ̀, ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ a sì máa bá a wá pàṣán. Ẹnu òmùgọ̀ ni yóo tì í sinu ìparun, ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ ni yóo sì ṣe tàkúté mú un. Ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ olófòófó dàbí òkèlè oúnjẹ dídùn, a máa wọni lára ṣinṣin. Ẹni tí ń ṣe ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀, ẹgbẹ́ ni òun ati ẹni tí ń ba nǹkan jẹ́. Orúkọ OLUWA jẹ́ ilé-ìṣọ́ tí ó lágbára, olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì yè. Ohun ìní ọlọ́rọ̀ ni ìlú olódi wọn, lójú wọn, ó dàbí odi ńlá tí ń dáàbò bò wọ́n. Ìgbéraga níí ṣáájú ìparun, ìrẹ̀lẹ̀ níí ṣáájú iyì. Ìwà òmùgọ̀ ni, ìtìjú sì ni, kí eniyan fèsì sí ọ̀rọ̀ kí ó tó gbọ́ ìdí rẹ̀. Eniyan lè farada àìsàn, ṣugbọn ta ló lè farada ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn? Ọkàn ọlọ́gbọ́n a máa fẹ́ ìmọ̀, etí ni ọlọ́gbọ́n fi wá a kiri. Ẹ̀bùn a máa ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ẹni tí ń fúnni lẹ́bùn, a sì mú un dé iwájú ẹni gíga. Ẹni tí ó bá kọ́kọ́ rojọ́ níí dàbí ẹni tí ó jàre, títí tí ẹnìkejì yóo fi bi í ní ìbéèrè, Gègé ṣíṣẹ́ a máa yanjú ọ̀rọ̀ a sì parí gbolohun asọ̀ láàrin àwọn alágbára. Ọkàn arakunrin tí eniyan bá ṣẹ̀ a máa le bí ìlú olódi, àríyànjiyàn sì dàbí ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn ilé ìṣọ́. Eniyan lè fi ọ̀rọ̀ ẹnu wá oúnjẹ fún ara rẹ̀, a lè jẹ oúnjẹ tí a bá fi ọ̀rọ̀ ẹnu wá ní àjẹyó ati àjẹṣẹ́kù. Ahọ́n lágbára láti pani ati láti lani, ẹni tí ó bá fẹ́ràn rẹ̀ yóo jèrè rẹ̀. Ẹni tí ó bá rí aya fẹ́ rí ohun rere, ó sì rí ojurere lọ́dọ̀ OLUWA. Ẹ̀bẹ̀ ni talaka bẹ̀, ṣugbọn ọlọ́rọ̀ á dáhùn tìkanra-tìkanra. Àwọn ọ̀rẹ́ kan wà, ọ̀rẹ́ àfẹnujẹ́ ni wọ́n, ṣugbọn ọ̀rẹ́ mìíràn wà tí ó fi ara mọ́ni ju ọmọ ìyá ẹni lọ. Talaka tí ń rìn pẹlu òtítọ́ inú, ó sàn ju òmùgọ̀ eniyan, tí ó ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn lọ. Kò dára kí eniyan wà láìní ìmọ̀, ẹni bá ń kánjú rìn jù a máa ṣìnà. Nígbà tí ìwà òmùgọ̀ bá kó ìparun bá a, ọkàn rẹ̀ a máa bá OLUWA bínú. Ọrọ̀ a máa mú kí eniyan ní ọpọlọpọ ọ̀rẹ́ titun, ṣugbọn àwọn ọ̀rẹ́ talaka a máa kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ẹlẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà, bẹ́ẹ̀ ni òpùrọ́ kò ní bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀san ibi. Ọ̀pọ̀ eniyan níí máa ń wá ojurere ẹni tó lawọ́, gbogbo eniyan sì ni ọ̀rẹ́ ẹni tí ń fúnni lẹ́bùn. Gbogbo àwọn arakunrin talaka ni wọ́n kórìíra rẹ̀, kí á má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jìnnà sí i! Ó fọ̀rọ̀ ẹnu fà wọ́n títí, sibẹ wọn kò súnmọ́ ọn. Ẹni tí ó ní ọgbọ́n fẹ́ràn ara rẹ̀, ẹni tí ó bá sì ní òye, yóo ṣe rere. Ẹlẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà, ẹni tí ó ń pa irọ́ yóo parun. Ìgbádùn kò yẹ òmùgọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò yẹ kí ẹrú jọba lórí àwọn ìjòyè. Ọgbọ́n kì í jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n yára bínú, ògo rẹ̀ sì níláti fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ dá. Ibinu ọba dàbí bíbú kinniun, ṣugbọn ojurere rẹ̀ dàbí ìrì lára koríko tútù. Òmùgọ̀ ọmọ lè kó ìparun bá baba rẹ̀, iyawo oníjà dàbí omi òjò tí ń kán tó, tó, tó, láì dáwọ́ dúró. A máa ń jogún ilé ati ọrọ̀ lọ́wọ́ baba ẹni, ṣugbọn OLUWA níí fúnni ní aya rere. Ìwà ọ̀lẹ a máa múni sùn fọnfọn, ebi níí sìí pa alápá-má-ṣiṣẹ́. Ẹni tí ó bá pa òfin mọ́, ẹ̀mí ara rẹ̀ ni ó pamọ́, ẹni tí ó kọ ọ̀nà Ọlọrun sílẹ̀ yóo kú. Ẹni tí ó ṣe ojurere fún àwọn talaka, OLUWA ni ó ṣe é fún, OLUWA yóo sì san ẹ̀san rẹ̀ fún un. Bá ọmọ rẹ wí nígbà tí ó sì lè gbọ́ ìbáwí, má sì ṣe wá ìparun rẹ̀. Onínúfùfù yóo jìyà inúfùfù rẹ̀, bí o bá gbà á sílẹ̀ lónìí, o níláti tún gbà á sílẹ̀ lọ́la. Gbọ́ ìmọ̀ràn kí o sì gba ẹ̀kọ́, kí o lè rí ọgbọ́n lò lẹ́yìn ọ̀la. Ọpọlọpọ ni èrò tí ó wà lọ́kàn ọmọ eniyan, ṣugbọn ìfẹ́ OLUWA ni àṣẹ. Ohun tí ayé ń fẹ́ lára eniyan ni òtítọ́ inú, talaka sì sàn ju òpùrọ́ lọ. Ìbẹ̀rù OLUWA a máa mú ìyè wá, ẹni tí ó ní i yóo ní ìfọ̀kànbalẹ̀, ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kan kò ní ṣẹlẹ̀ sí i. Ọ̀lẹ ti ọwọ́ bọ àwo oúnjẹ, ṣugbọn kò lè bu oúnjẹ sí ẹnu ara rẹ̀. Na pẹ̀gànpẹ̀gàn eniyan, òpè yóo sì kọ́gbọ́n. Bá olóye wí, yóo sì ní ìmọ̀ sí i. Ẹni tí ó bá kó baba rẹ̀ nílé, tí ó sì lé ìyá rẹ̀ jáde, ọmọ tíí fa ìtìjú ati àbùkù báni ni. Ọmọ mi, bí o bá kọ etí dídi sí ẹ̀kọ́, o óo ṣìnà kúrò ninu ìmọ̀. Ẹlẹ́rìí èké a máa kẹ́gàn ìdájọ́ òtítọ́, eniyan burúkú a máa jẹ ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹni jẹun. Ìjìyà ti wà nílẹ̀ fún ẹlẹ́yà, a sì ti tọ́jú pàṣán sílẹ̀ fún ẹ̀yìn òmùgọ̀. Ẹlẹ́yà ni ọtí waini, aláriwo ní ọtí líle, ẹnikẹ́ni tí a bá fi tànjẹ kò gbọ́n. Ibinu ọba dàbí bíbú kinniun, ẹni tí ó bá mú ọba bínú fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu. Nǹkan iyì ni pé kí eniyan máa yẹra fún ìjà, ṣugbọn òmùgọ̀ eniyan níí máa ń jà. Ọ̀lẹ kì í dáko ní àkókò, nítorí náà, nígbà ìkórè, kò ní rí nǹkankan kó jọ. Èrò ọkàn eniyan dàbí omi jíjìn, ẹni tí ó bá ní ìmọ̀ ló lè fà á jáde. Ọ̀pọ̀ eniyan a máa ka ara wọn kún olóòótọ́, ṣugbọn níbo la ti lè rí ẹyọ ẹnìkan tó jẹ́ olódodo? Olódodo a máa rìn ní ọ̀nà òtítọ́, ibukun ni fún àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n tẹ̀lé e. Nígbà tí ọba bá jókòó sórí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀, ojú ni yóo fi gbọn àwọn ẹni ibi dànù. Ta ló lè sọ pé ọkàn òun mọ́, ati pé òun mọ́, òun kò ní ẹ̀ṣẹ̀? Ayédèrú òṣùnwọ̀n jẹ́ ohun ìríra lójú OLUWA. Ọmọde pàápàá a máa fi irú eniyan tí òun jẹ́ hàn nípa ìṣe rẹ̀, bí ohun tí ó ṣe dára, tí ó sì tọ̀nà. Ati etí tí ń gbọ́ràn, ati ojú tí ń ríran, OLUWA ló dá ekinni-keji wọn. Má fẹ́ràn oorun àsùnjù, kí o má baà di talaka, lajú, o óo sì ní oúnjẹ ní àníṣẹ́kù. “Èyí kò dára, kò dára” ni ẹni tí ń rajà máa ń wí, bí ó bá lọ tán, a máa fọ́nnu ọjà ọ̀pọ̀ tí ó rà. Wúrà ń bẹ, òkúta olówó iyebíye sì wà lọpọlọpọ, ṣugbọn ọ̀rọ̀ ìmọ̀ ni ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye. Gba ẹ̀wù ẹni tí ó bá ṣe onídùúró fún àlejò, gba aṣọ ẹni tí ó ṣe onígbọ̀wọ́ ẹni tí kò mọ̀ rí. Oúnjẹ tí a bá rí lọ́nà èrú máa ń dùn lẹ́nu eniyan, ṣugbọn nígbà tí a bá jẹ ẹ́ tán, ẹnu ẹni a máa kan. Ìmọ̀ràn níí fìdí ètò múlẹ̀, gba ìtọ́sọ́nà kí o tó lọ jagun. Ẹni tí ó ń ṣe òfófó káàkiri a máa tú ọpọlọpọ àṣírí, nítorí náà má ṣe bá ẹlẹ́jọ́ kẹ́gbẹ́. Bí eniyan bá ń fi baba tabi ìyá rẹ̀ bú, àtùpà rẹ̀ yóo kú láàrin òkùnkùn biribiri. Ogún tí a fi ìkánjú kójọ níbẹ̀rẹ̀, kì í ní ibukun nígbẹ̀yìn. Má sọ pé o fẹ́ fi burúkú san burúkú, gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, yóo sì gbà ọ́. Ayédèrú òṣùnwọ̀n jẹ́ ohun ìríra lójú OLUWA, ìwọ̀n èké kò dára. OLUWA ní ń tọ́ ìṣísẹ̀ ẹni, eniyan kò lè ní òye ọ̀nà ara rẹ̀. Ronú jinlẹ̀ kí o tó jẹ́jẹ̀ẹ́ fún OLUWA, kí o má baà kábàámọ̀ rẹ̀. Ọba tó gbọ́n a máa fẹ́ eniyan burúkú dànù, a sì lọ̀ wọ́n mọ́lẹ̀. Ẹ̀mí eniyan ni fìtílà OLUWA, tíí máa wá gbogbo kọ́lọ́fín inú rẹ̀ kiri. Ìfẹ́ ati òtítọ́ níí mú kí ọba pẹ́, òdodo níí sì ń gbé ìjọba rẹ̀ ró. Agbára ni ògo ọ̀dọ́, ewú sì ni ẹwà àgbà. Ìjìyà tó fa ọgbẹ́ a máa mú ibi kúrò, pàṣán a máa mú kí inú mọ́. Orísun omi ni ọkàn ọba lọ́wọ́ OLUWA, ibi tí ó bá wu Oluwa ni ó ń darí rẹ̀ sí. Gbogbo ọ̀nà eniyan ni ó dára lójú ara rẹ̀, ṣugbọn ọkàn ni OLUWA ń wò. Kí eniyan ṣe òdodo ati ẹ̀tọ́, sàn ju ẹbọ lọ lójú OLUWA. Bíi fìtílà ẹni ibi ni gbígbé ojú gangan ati ìgbéraga, ẹ̀ṣẹ̀ sì ni wọ́n. Dájúdájú èrò ẹni tí ó ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn yóo yọrí sí ọ̀pọ̀, ṣugbọn ẹni tí ó bá ń kánjú jù kò ní ní ànító. Fífi èké kó ìṣúra jọ dàbí lílé ìkùukùu, ó sì jẹ́ tàkúté ikú. Ìwà ipá àwọn ẹni ibi ni yóo gbá wọn dànù, nítorí pé wọ́n kọ̀ láti ṣe òtítọ́. Ọ̀nà ẹlẹ́bi kì í gún, ṣugbọn ìrìn aláìlẹ́bi a máa tọ́. Ó sàn láti máa gbé kọ̀rọ̀ kan lókè àjà, ju pé kí eniyan máa bá oníjàngbọ̀n obinrin gbé ilé lọ. Ibi ni ọkàn eniyan burúkú máa ń fẹ́, àwọn aládùúgbò rẹ̀ kì í sìí rí ojurere rẹ̀. Ìjìyà ẹlẹ́yà a máa mú kí òpè gbọ́n, tí a bá ń kọ́ ọlọ́gbọ́n, yóo ní ìmọ̀ sí i. Olódodo ṣàkíyèsí ilé eniyan burúkú, eniyan burúkú sì bọ́ sinu ìparun. Ẹni tí ó kọ etí dídi sí igbe talaka, òun náà yóo kígbe, ṣugbọn kò ní rí ẹni dá a lóhùn. Ẹ̀bùn tí a fúnni ní kọ̀rọ̀ a máa paná ibinu, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tí a tì bọ abẹ́ aṣọ a máa paná ìjà. Tí a bá ṣe ìdájọ́ òtítọ́, inú olódodo a dùn, ṣugbọn ìfòyà ni fún àwọn aṣebi. Ẹni tí ó sá kúrò lọ́nà òye yóo sinmi láàrin àwọn òkú. Ẹni tí ó fẹ́ràn fàájì yóo di talaka, ẹni tí ó fẹ́ràn ọtí waini ati òróró kò ní lówó lọ́wọ́. Eniyan burúkú ni yóo forí gba ibi tíì bá dé bá olódodo. Alaiṣootọ ni yóo fara gba ìyà tí ó tọ́ sí olóòótọ́ inú. Ó sàn láti máa gbé ààrin aṣálẹ̀, ju kí eniyan máa bá oníjà ati oníkanra obinrin gbé lọ. Ní ilé ọlọ́gbọ́n ni à á tí ń bá nǹkan olówó iyebíye, ṣugbọn òmùgọ̀ a máa ba tirẹ̀ jẹ́. Ẹni tí ń lépa òdodo ati àánú yóo rí ìyè, òdodo, ati iyì. Ọlọ́gbọ́n a máa gba ìlú àwọn alágbára a sì wó ibi ààbò tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé lulẹ̀. Ẹni tí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́ pa ara rẹ̀ mọ́ kúrò ninu ìyọnu. “Oníyẹ̀yẹ́” ni orúkọ ẹni tí ń gbéraga, tí ó sì ń ṣe mo tó báyìí-dà báyìí. Ìrònú ohun tí ọ̀lẹ fẹ́ ni yóo pa á, nítorí ọwọ́ rẹ̀ kọ̀ láti ṣiṣẹ́. Eniyan burúkú a máa ṣe ojúkòkòrò ní gbogbo ìgbà, ṣugbọn olódodo ń fúnni láìdáwọ́dúró. Ohun ìríra ni ẹbọ eniyan burúkú, pàápàá tí ó bá mú un wá pẹlu èrò ibi. Ọ̀rọ̀ ẹlẹ́rìí èké yóo di asán, ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹni tí ó fetí sílẹ̀ ni a óo gbàgbọ́. Eniyan burúkú a máa lo ògbójú, ṣugbọn olóòótọ́ máa ń yẹ ọ̀nà ara rẹ̀ wò. Kò sí ọgbọ́n, tabi òye, tabi ìmọ̀, tí ó lè dojú kọ OLUWA kí ó mókè. Eniyan a máa tọ́jú ẹṣin sílẹ̀ de ọjọ́ ogun, ṣugbọn OLUWA ló ni ìṣẹ́gun. Orúkọ rere dára láti yàn ju ọrọ̀ pupọ lọ, kí á rí ojurere sì dára ju kí á ní fadaka ati wúrà lọ. Ọlọ́rọ̀ ati talaka pàdé, OLUWA ló dá ekinni-keji wọn. Ọlọ́gbọ́n rí ibi, ó farapamọ́, ṣugbọn òpè ń bá tirẹ̀ lọ láìbìkítà, ó sì kó sinu ìyọnu. Èrè ìrẹ̀lẹ̀ ati ìbẹ̀rù OLUWA ni ọrọ̀, ọlá, ati ìyè. Ẹ̀gún ati tàkúté ń bẹ lọ́nà àwọn ẹlẹ́tàn, ẹni tí ó pa ọkàn rẹ̀ mọ́ yóo jìnnà sí wọn. Tọ́ ọmọ rẹ sí ọ̀nà tí ó yẹ kí ó máa rìn, bí ó bá dàgbà tán, kò ní kúrò ninu rẹ̀. Ọlọ́rọ̀ máa ń jọba lé talaka lórí, ẹni tí ó lọ yá owó sì ni ẹrú ẹni tí ó yá a lówó. Ẹni tí ó bá gbin aiṣododo yóo kórè ìdààmú, pàṣán ibinu rẹ̀ yóo sì parun. Olójú àánú yóo rí ibukun gbà, nítorí pé ó ń fún talaka ninu oúnjẹ rẹ̀. Lé pẹ̀gànpẹ̀gàn síta, ìjà yóo rọlẹ̀, asọ̀ ati èébú yóo sì dópin. Ẹni tí ó fẹ́ ọkàn mímọ́, tí ó sì ní ọ̀rọ̀ rere lẹ́nu yóo bá ọba ṣọ̀rẹ́. Ojú OLUWA ń ṣọ́ ìmọ̀ tòótọ́, ṣugbọn a máa yí ọ̀rọ̀ àwọn alaigbagbọ po. Ọ̀lẹ a máa sọ pé, “Kinniun wà níta! Yóo pa mí jẹ lójú pópó!” Ẹnu alágbèrè obinrin dàbí kòtò ńlá, ẹni tí OLUWA bá ń bínú sí níí já sinu rẹ̀. Ìwà agídí dì sí ọkàn ọmọde, ṣugbọn pàṣán ìbáwí níí lé e jáde. Ẹni tí ó ni talaka lára kí ó lè ní ohun ìní pupọ, tabi tí ó ń ta ọlọ́rọ̀ lọ́rẹ yóo pada di talaka. Tẹ́tí rẹ sílẹ̀ kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n, kí o sì fi ọkàn sí ẹ̀kọ́ mi, nítorí yóo dára tí o bá pa wọ́n mọ́ lọ́kàn rẹ, tí o sì ń fi wọ́n ṣe ọ̀rọ̀ sọ jáde. Ìwọ ni mo sọ wọ́n di mímọ̀ fún lónìí, àní ìwọ, kí ó le jẹ́ pé OLUWA ni o gbẹ́kẹ̀lé. Ṣebí mo ti kọ ọgbọ̀n àkọsílẹ̀ fún ọ lórí ìmọ̀ràn ati ọgbọ́n, láti fi ohun tí ó tọ̀nà tí ó sì jẹ́ òtítọ́ hàn ọ́, kí o lè fi ìdáhùn pípé fún ẹni tí ó rán ọ. Má ja talaka lólè, nítorí pé ó jẹ́ talaka, má sì dájọ́ èké fún ẹni tí ara ń ni. Nítorí OLUWA yóo gbèjà wọn, yóo fìyà jẹ àwọn tí wọn ń jẹ wọ́n níyà. Má bá oníbìínú eniyan kẹ́gbẹ́, má sì bá onínúfùfù da nǹkan pọ̀. Kí o má baà kọ́ ìwà rẹ̀, kí o sì fi tàkúté mú ara rẹ. Má bá wọn ṣe onígbọ̀wọ́ ẹni tó fẹ́ yá owó, má bá wọn ṣe onídùúró fún onígbèsè. Tí o kò bá rí owó san fún olówó, olówó lè pé kí wọn gba ibùsùn rẹ. Má hú ohun tí àwọn baba ńlá rẹ rì mọ́lẹ̀, tí wọ́n fi pa ààlà kúrò. Ṣe akiyesi ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ rẹ̀, àwọn ọba ni yóo máa bá ṣiṣẹ́, kì í ṣe àwọn eniyan lásán. Nígbà tí o bá jókòó láti bá ìjòyè jẹun, kíyèsí ẹni tí ó bá wà níwájú rẹ dáradára. Tí o bá jẹ́ wọ̀bìà eniyan, ṣọ́ra, kí o má fi ọ̀bẹ lé ara rẹ lọ́fun. Má jẹ́ kí oúnjẹ aládìídùn rẹ̀ wọ̀ ọ́ lójú, nítorí ó lè jẹ́ oúnjẹ ẹ̀tàn. Má ṣe làálàá àṣejù láti kó ọrọ̀ jọ, fi ọgbọ́n sẹ́ ara rẹ. Kí o tó ṣẹ́jú pẹ́, owó rẹ lè ti lọ, ó le gúnyẹ̀ẹ́ kí ó fò, bí ìgbà tí ẹyẹ àṣá bá fò lọ. Má ṣe jẹ oúnjẹ ahun, má ní ìfẹ́ sí oúnjẹ aládìídùn rẹ̀; nítorí ẹni tí ó máa fi ọkàn ṣírò owó oúnjẹ ni. Ó lè máa wí fún ọ pé, “Jẹ, kí o sì mu!” ṣugbọn kò dé inú rẹ̀. O óo pọ gbogbo òkèlè tí o jẹ, gbogbo ọ̀rọ̀ dídùn tí o sọ yóo sì jẹ́ àsọdànù. Má sọ̀rọ̀ létí òmùgọ̀, nítorí yóo gan ọgbọ́n tí ó wà ninu ọ̀rọ̀ tí o sọ. Má ṣe hú ohun tí wọ́n rì mọ́lẹ̀ fi pa ààlà láti ìgbà àtijọ́, má sì gba ilẹ̀ ọmọ aláìníbaba; nítorí pé Olùràpadà wọn lágbára, yóo gba ìjà wọn jà. Fi ọkàn rẹ sí ẹ̀kọ́, kí o sì tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ ìmọ̀. Bá ọmọde wí; bí o bá fi pàṣán nà án, kò ní kú. Bí o bá fi pàṣán nà án, o óo gba ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́ ikú. Ọmọ mi, bí o bá gbọ́n, inú mi yóo dùn. N óo láyọ̀ ninu ọkàn mi nígbà tí o bá ń sọ òtítọ́. Má ṣe ìlara àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn máa bẹ̀rù OLUWA lọ́jọ́ gbogbo. Dájúdájú, ọjọ́ ọ̀la rẹ yóo dára, ìrètí rẹ náà kò sì ní já sí òfo. Fetí sí mi, ọmọ mi, kí o sì gbọ́n, darí ọkàn rẹ sí ọ̀nà títọ́. Má bá àwọn ọ̀mùtí kẹ́gbẹ́; tabi àwọn wọ̀bìà, tí wọn ń jẹ ẹran ní àjẹkì; nítorí pé àwọn ọ̀mùtí ati àwọn wọ̀bìà yóo di talaka, oorun àsùnjù a sì máa sọ eniyan di alákìísà. Gbọ́ ti baba tí ó bí ọ, má sì ṣe pẹ̀gàn ìyá rẹ nígbà tí àgbà bá dé sí i. Ra òtítọ́, má sì tà á, ra ọgbọ́n, ẹ̀kọ́ ati òye pẹlu. Baba olódodo ọmọ yóo láyọ̀ pupọ, inú ẹni tí ó bí ọlọ́gbọ́n ọmọ yóo dùn. Mú inú baba ati ìyá rẹ dùn, jẹ́ kí ìyá tí ó bí ọ láyọ̀ lórí rẹ. Ọmọ mi, gbọ́ tèmi, kí o sì máa kíyèsí ọ̀nà mi. Nítorí aṣẹ́wó dàbí ọ̀fìn jíjìn, obinrin onírìnkurìn sì dàbí kànga tí ó jìn. A máa ba níbùba bí olè, a sì máa sọ ọpọlọpọ ọkunrin di alágbèrè. Ta ló ni òṣì? Ta ló ni ìbànújẹ́? Ta ló ni ìjà? Ta ló ni asọ̀? Ta ló ni ọgbẹ́ láìnídìí? Ta ló ni ojú pípọ́n koko? Àwọn tí wọn máa ń pẹ́ ní ìdí ọtí ni, àwọn tí wọn ń mu ọtí àdàlú. Má jẹ́ kí pípọ́n tí ọtí pọ́n fà ọ́ mọ́ra, nígbà tí ó bá ń ta wínníwínní ninu ife, tí o dà á mu, tí ó lọ geere lọ́nà ọ̀fun. Nígbà tí ó bá yá, á máa buni ṣán bí ejò, oró rẹ̀ á sì dàbí ti ejò paramọ́lẹ̀. Ojú rẹ yóo rí nǹkan àjèjì, ọkàn rẹ á máa ro èròkerò. O óo dàbí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ lórí agbami òkun, bí ẹni tí ó sùn lórí òpó ọkọ̀. O óo wí pé, “Wọ́n lù mi, ṣugbọn kò dùn mí; wọ́n nà mí, ṣugbọn ń kò mọ̀. Nígbà wo ni n óo tó jí? N óo tún wá ọtí mìíràn mu.” Má ṣe ìlara àwọn ẹni ibi, má sì ṣe bá wọn kẹ́gbẹ́, nítorí ọkàn wọn ń gbèrò ìparun, ẹnu wọn sì ń sọ̀rọ̀ ìkà. Ọgbọ́n ni a fi ń kọ́lé, òye ni a fi ń fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀. Pẹlu ìmọ̀ ni eniyan fi í kó oniruuru nǹkan ìní dáradára olówó iyebíye kún àwọn yàrá rẹ̀ Ọlọ́gbọ́n lágbára ju akọni lọ, ẹni tí ó ní ìmọ̀ sì ju alágbára lọ. Nítorí nípa ìtọ́ni ọlọ́gbọ́n, o lè jagun, ọpọlọpọ ìmọ̀ràn níí sìí mú ìṣẹ́gun wà. Ọgbọ́n ga jù fún òmùgọ̀, kì í lè lanu sọ̀rọ̀ láwùjọ. Ẹni tí ń pète àtiṣe ibi ni a óo máa pè ní oníṣẹ́ ibi. Ẹ̀ṣẹ̀ ni ète òmùgọ̀, ẹni ìríra sì ni pẹ̀gànpẹ̀gàn. Bí o bá kùnà lọ́jọ́ ìpọ́njú, a jẹ́ pé agbára rẹ kò tó. Gba àwọn tí wọ́n bá fẹ́ lọ pa sílẹ̀, fa àwọn tí wọ́n bá fẹ́ ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n, lọ sọ́dọ̀ àwọn apànìyàn pada. Bí ẹ bá sọ pé ẹ kò mọ nǹkan nípa rẹ̀, ṣé ẹni tí ó mọ èrò ọkàn kò rí i? Ṣé ẹni tí ń pa ẹ̀mí rẹ mọ́ kò mọ̀, àbí kò ní san án fún eniyan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀? Ọmọ mi, jẹ oyin, nítorí pé ó dùn, oyin tí a fún láti inú afárá a sì máa dùn lẹ́nu. Mọ̀ dájú pé bẹ́ẹ̀ ni ọgbọ́n yóo rí fún ọ, bí o bá ní i, yóo dára fún ọ lẹ́yìn ọ̀la, ìrètí rẹ kò sì ní di asán. Má lúgọ bí eniyan burúkú láti kó ilé olódodo, má fọ́ ilé rẹ̀. Nítorí pé bí olódodo bá ṣubú léra léra nígbà meje, yóo tún dìde, ṣugbọn àjálù máa ń bi ẹni ibi ṣubú. Má yọ̀ nígbà tí ọ̀tá rẹ bá ṣubú, má sì jẹ́ kí inú rẹ dùn bí ó bá kọsẹ̀, kí OLUWA má baà bínú sí ọ tí ó bá rí ọ, kí ó sì yí ojú ibinu rẹ̀ pada kúrò lára ọ̀tá rẹ. Má ṣe kanra nítorí àwọn aṣebi, má sì ṣe jowú eniyan burúkú, nítorí pé kò sí ìrètí fún ẹni ibi, a óo sì pa àtùpà eniyan burúkú. Ọmọ mi, bẹ̀rù OLUWA ati ọba, má ṣe àìgbọràn sí ọ̀kankan ninu wọn; nítorí jamba lè ti ọ̀dọ̀ wọn wá lójijì, ta ló mọ irú ìparun, tí ó lè ti ọ̀dọ̀ àwọn mejeeji wá? Àwọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n tún nìwọ̀nyí: Kò dára láti máa ṣe ojuṣaaju ninu ìdájọ́. Ẹni tí ó sọ fún ẹlẹ́ṣẹ̀ pé ọwọ́ rẹ̀ mọ́, àwọn eniyan yóo gbé e ṣépè, àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì kórìíra rẹ̀. Ṣugbọn yóo dára fún àwọn tí wọ́n bá dá ẹ̀bi fún ẹni tí ó jẹ̀bi, ibukun Ọlọrun yóo sì bá wọn. Ẹni tí ó bá fèsì tí ó tọ́ dàbí ẹni tí ó fi ẹnu koni lẹ́nu. Parí iṣẹ́ tí ò ń ṣe níta, tọ́jú gbogbo nǹkan oko rẹ, lẹ́yìn náà kọ́ ilé rẹ. Má jẹ́rìí lòdì sí aládùúgbò rẹ láìnídìí, má sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ti ẹnu rẹ jáde. Má sọ pé, “Bí lágbájá ti ṣe sí mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi náà yóo ṣe sí i, n óo san ẹ̀san ohun tí ó ṣe fún un.” Mo gba ẹ̀gbẹ́ oko ọ̀lẹ kan kọjá, mo kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọgbà àjàrà ẹnìkan tí kò lóye. Wò ó! Ẹ̀gún ti hù níbi gbogbo, igbó ti bo gbogbo rẹ̀ mọ́lẹ̀, ọgbà tí ó fi òkúta ṣe yí i ká sì ti wó. Mo ṣe àṣàrò lórí ohun tí mo ṣàkíyèsí, mo sì kọ́ ẹ̀kọ́ lára ohun tí mo rí. Oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀, ìkáwọ́ gbera díẹ̀ láti sinmi, bẹ́ẹ̀ ni òṣì yóo ṣe dé bá ọ bíi kí olè yọ sí eniyan, àìní yóo sì wọlé tọ̀ ọ́ bí ẹni tí ó di ihamọra ogun. Àwọn òwe mìíràn tí Solomoni pa, tí àwọn òṣìṣẹ́ Hesekaya ọba Juda kọ sílẹ̀ nìwọ̀nyí. Ògo ni ó jẹ́ fún Ọlọrun láti fi nǹkan pamọ́, ṣugbọn ògo ló sá tún jẹ́ fún ọba láti wádìí nǹkan ní àwárí. Bí ọ̀run ti ga, tí ilẹ̀ sì jìn, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò lè mọ ohun tí ó wà lọ́kàn àwọn ọba. Yọ́ gbogbo ìdọ̀tí tí ó wà lára fadaka kúrò, alágbẹ̀dẹ yóo sì rí fadaka fi ṣe ohun èlò. Mú àwọn olùdámọ̀ràn ibi kúrò lọ́dọ̀ ọba, a óo sì fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ pẹlu òdodo. Má ṣe gbéraga níwájú ọba, tabi kí o jókòó ní ipò àwọn eniyan pataki, nítorí ó sàn kí ó wí fún ọ pé, “Máa bọ̀ lókè níhìn-ín”, jù pé kí ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ níwájú ọlọ́lá kan lọ. Má fi ìwàǹwára fa ẹnikẹ́ni lọ sílé ẹjọ́, nítorí kí ni o óo ṣe nígbà tí aládùúgbò rẹ bá dójútì ọ́. Bí o bá ń bá aládùúgbò rẹ ṣe àríyànjiyàn má ṣe tú àṣírí ẹlòmíràn, kí ẹni tí ó bá gbọ́ má baà dójútì ọ́, kí o má baà sọ ara rẹ lórúkọ. Ọ̀rọ̀ tí a sọ lákòókò tí ó yẹ dàbí ohun ọ̀ṣọ́ wúrà tí a gbé sinu àwo fadaka. Ìbáwí ọlọ́gbọ́n dàbí òrùka wúrà, tabi ohun ọ̀ṣọ́ tí a fi wúrà ṣe, fún ẹni tí ó ní etí láti fi gbọ́. Bí òtútù yìnyín nígbà ìkórè, bẹ́ẹ̀ ni olóòótọ́ iranṣẹ jẹ́, sí àwọn tí ó rán an, a máa fi ọkàn àwọn oluwa rẹ̀ balẹ̀. Bí òjò tí ó ṣú dudu tí ó fẹ́ atẹ́gùn títí ṣugbọn tí kò rọ̀, ni ẹni tí ó ń fọ́nnu láti fúnni lẹ́bùn, tí kò sì fúnni ní nǹkankan. Pẹlu sùúrù, a lè yí aláṣẹ lọ́kàn pada ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ sì lè fọ́ eegun. Bí o bá rí oyin, lá a níwọ̀nba, má lá a ní àlájù, kí o má baà bì. Má máa lọ sílé aládùúgbò rẹ lemọ́lemọ́, kí ọ̀rọ̀ rẹ má baà sú u, kí ó sì kórìíra rẹ. Ẹni tí ó jẹ́rìí èké nípa aládùúgbò rẹ̀ dàbí kùmọ̀ ọmọ ogun, tabi idà, tabi ọfà tí ó mú. Igbẹkẹle ninu alaiṣootọ ní àkókò ìṣòro, dàbí eyín tí ń ro ni, tabi ẹsẹ̀ tí ó rọ́. Bí ẹni tí a bọ́ṣọ rẹ̀ ninu òtútù, tabi tí a da ọtí kíkan sójú egbò rẹ̀, ni ẹni tí à ń kọrin fún ní àkókò tí inú rẹ̀ bàjẹ́. Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ, bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mu. Nípa bẹ́ẹ̀ o óo wa ẹ̀yinná lé e lórí, OLUWA yóo sì san ẹ̀san rere fún ọ. Bí ẹ̀fúùfù ìhà àríwá tíí mú òjò wá, bẹ́ẹ̀ ni òfófó ṣíṣe máa ń fa kí a máa fi ojú burúkú woni. Ó sàn kí á máa gbé kọ̀rọ̀ kan lókè àjà, ju pé kí eniyan máa bá oníjàngbọ̀n obinrin gbé ilé lọ. Gẹ́gẹ́ bí omi tútù ti rí fún ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ, ni ìròyìn ayọ̀ láti ilẹ̀ òkèèrè rí. Olódodo tí ó fi ààyè sílẹ̀ fún eniyan burúkú dàbí odò tí omi rẹ̀ dàrú tabi kànga tí a da ìdọ̀tí sí. Kò dára kí eniyan lá oyin ní àlájù, bẹ́ẹ̀ ni kò dára kí eniyan máa wá iyì ní àwájù. Ẹni tí kò lè kó ara rẹ̀ níjàánu, dàbí ìlú tí ọ̀tá wọ̀, tí wọ́n sì wó odi rẹ̀ lulẹ̀. Bí yìnyín kò ṣe yẹ ní àkókò ooru, ati òjò ní àkókò ìkórè, bẹ́ẹ̀ ni iyì kò yẹ òmùgọ̀. Bí ológoṣẹ́ tí ń rábàbà kiri, ati bí alápàáǹdẹ̀dẹ̀ tí ń fò ká, bẹ́ẹ̀ ni èpè tí kò nídìí, kì í balẹ̀ síbìkan. Bí pàṣán ti rí lára ẹṣin, tí ìjánu sì rí lẹ́nu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, bẹ́ẹ̀ ni igi rí lẹ́yìn àwọn òmùgọ̀. Má ṣe dá òmùgọ̀ lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀, kí ìwọ pàápàá má baà dàbí rẹ̀. Dá òmùgọ̀ lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà agọ̀ rẹ̀, kí ó má baà rò pé òun gbọ́n lójú ara òun. Ẹni tí ó rán òmùgọ̀ níṣẹ́ gé ara rẹ̀ lẹ́sẹ̀, ó sì ń mu omi ìjàngbọ̀n. Bí ẹsẹ̀ arọ, tí kò wúlò, ni òwe rí lẹ́nu òmùgọ̀. Bí ẹni fi òkúta sinu kànnàkànnà, ni ẹni tí ń yẹ́ òmùgọ̀ sí rí. Bí ẹ̀gún tí ó gún ọ̀mùtí lọ́wọ́, ni òwe rí lẹ́nu òmùgọ̀. Ẹni tí ó gba òmùgọ̀ tabi ọ̀mùtí sí iṣẹ́ dàbí tafàtafà tí ń pa eniyan lára kiri. Bí ajá tíí pada sídìí èébì rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni òmùgọ̀ tó pada sí ìwà agọ̀ rẹ̀. Ìrètí ń bẹ fún òmùgọ̀ ju ẹni tí ó gbọ́n lójú ara rẹ̀ lọ. Ọ̀lẹ ń wí pé, “Kinniun kan wà lọ́nà! Kinniun buburu kan wà ní ìgboro!” Bí ìlẹ̀kùn ṣe ń ṣí síhìn-ín, sọ́hùn-ún, lórí ìdè rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ ń yí síhìn-ín, sọ́hùn-ún, lórí ibùsùn rẹ̀. Ọ̀lẹ ti ọwọ́ bọ àwo oúnjẹ, ṣugbọn ó lẹ kọjá kí ó lè bu oúnjẹ kí ó fi bọ ẹnu. Ọ̀lẹ gbọ́n lójú ara rẹ̀ ju eniyan meje tí wọ́n lè dáhùn ọ̀rọ̀ pẹlu ọgbọ́n lọ. Ẹni tí ó ti ọrùn bọ ìjà tí kì í ṣe tirẹ̀, dàbí ẹni tí ó gbá ajá alájá létí mú. Bíi aṣiwèrè tí ó ju igi iná tabi ọfà olóró, ni ẹni tó ṣi ẹlòmíràn lọ́nà, tí ó wá ń sọ pé “Mo kàn ń ṣeré ni!” Láìsí igi, iná óo kú, bẹ́ẹ̀ ni, láìsí olófòófó, ìjà óo tán. Bí èédú ti rí sí ògúnná, ati igi sí iná, bẹ́ẹ̀ ni oníjà eniyan rí, sí àtidá ìjà sílẹ̀. Ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ olófòófó dàbí òkèlè oúnjẹ dídùn a máa wọni lára ṣinṣin. Ètè mímú ati inú burúkú, dàbí ìdàrọ́ fadaka tí a yọ́ bo ìkòkò amọ̀. Ẹni tí ó bá kórìíra eniyan, lè máa fi ọ̀rọ̀ ẹnu bo ara rẹ̀ láṣìírí, ṣugbọn ẹ̀tàn wà ninu rẹ̀, bí ó bá sọ̀rọ̀ dáradára, má ṣe gbà á gbọ́, nítorí ọpọlọpọ ìríra kún inú ọkàn rẹ̀. Ó lè gbìyànjú láti fi ẹ̀tàn pa àrankàn rẹ̀ mọ́, ṣugbọn ìwà burúkú rẹ̀ yóo hàn ní àwùjọ gbogbo eniyan. Ẹni tí ó bá gbẹ́ kòtò, ni yóo já sinu rẹ̀, ẹni tí ó bá sì ń yí òkúta ni òkúta yóo pada yí lù. A-purọ́-mọ́ni a máa kórìíra àwọn tí ń parọ́ mọ́, ẹni tí ń pọ́nni sì lè fa ìparun ẹni. Má lérí nípa ọ̀la, nítorí o kò mọ ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Ẹlòmíràn ni kí o jẹ́ kí ó yìn ọ́, má yin ara rẹ, jẹ́ kí ó ti ẹnu ẹlòmíràn jáde, kí ó má jẹ́ láti ẹnu ìwọ alára. Òkúta wúwo, yanrìn sì tẹ̀wọ̀n, ṣugbọn ìmúnibínú aṣiwèrè wúwo lọ́kàn ẹni ju mejeeji lọ. Ìkà ni ibinu, ìrúnú sì burú lọpọlọpọ, ṣugbọn, ta ló lè dúró níwájú owú jíjẹ? Ìbáwí ní gbangba sàn ju ìfẹ́ kọ̀rọ̀ lọ. Òtítọ́ ọ̀rọ̀ ọ̀rẹ́ ẹni lè dunni bí ọgbẹ́; ṣugbọn ẹ̀tàn ni ìfẹnukonu ọ̀tá. Ẹni tí ó yó lè wo oyin ní àwòmọ́jú, ṣugbọn bí nǹkan tilẹ̀ korò a máa dùn, lẹ́nu ẹni tí ebi ń pa. Ẹni tí ó ṣìnà ilé rẹ̀, dàbí ẹyẹ tí ó ṣìnà ìtẹ́ rẹ̀. Òróró ati turari a máa mú inú dùn, ṣugbọn láti inú ìmọ̀ràn òtítọ́ ni adùn ọ̀rẹ́ ti ń wá. Má pa àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tì ati àwọn ọ̀rẹ́ baba rẹ; má sì lọ sí ilé arakunrin rẹ ní ọjọ́ ìṣòro rẹ. Nítorí pé aládùúgbò tí ó súnmọ́ ni sàn ju arakunrin tí ó jìnnà sí ni lọ. Ọmọ mi, gbọ́n, kí o sì mú inú mi dùn, kí n lè rí ẹnu dá àwọn tí wọn ń pẹ̀gàn mi lóhùn. Amòye eniyan rí ewu, ó sì fi ara rẹ̀ pamọ́, ṣugbọn òpè kọjá lọ láàrin rẹ̀, ó sì jìyà rẹ̀. Gba ẹ̀wù ẹni tí ó bá ṣe onídùúró fún àlejò, kí o sì gba nǹkan ìdógò lọ́wọ́ rẹ̀, tí ó bá ṣe onídùúró fún àjèjì obinrin. Ẹni tí ó jí ní kutukutu òwúrọ̀, tí ó ń fi ariwo kí aládùúgbò rẹ̀, kò yàtọ̀ sí ẹni tí ń ṣépè. Iyawo oníjà dàbí omi òjò, tí ń kán tó! Tó! Tó! Láì dáwọ́ dúró; ẹni tí bá ń gbìyànjú láti dá irú obinrin bẹ́ẹ̀ lẹ́kun dàbí ẹni tí ń gbìyànjú láti dá afẹ́fẹ́ dúró, tabi ẹni tó fẹ́ fi ọwọ́ mú epo. Bí irin ti ń pọ́n irin, bẹ́ẹ̀ ni eniyan ń kẹ́kọ̀ọ́ lára ẹnìkejì rẹ̀. Ẹni tí ń tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ yóo rí èso rẹ̀ jẹ, ẹni tí ń tọ́jú ọ̀gá rẹ̀ yóo gba ìyìn rẹ̀. Bí omi tíí fi bí ojú ẹni ti rí han ni, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn eniyan ń fi irú ẹni tí eniyan jẹ́ hàn. Ìparun ati isà òkú kò lè ní ìtẹ́lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ náà ni ojú eniyan, kì í ní ìtẹ́lọ́rùn. Iná ni a fi ń dán wúrà ati fadaka wò, ìyìn ni a fi ń dán eniyan wò. Wọn ì báà ju òmùgọ̀ sinu odó, kí wọn fi ọmọ odó gún un pọ̀ mọ́ ọkà, ẹnìkan kò lè gba ìwà òmùgọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. Rí i dájú pé o mọ̀ bí agbo ẹran rẹ ti rí, sì máa tọ́jú ọ̀wọ́ ẹran rẹ dáradára; nítorí ọrọ̀ kì í pẹ́ lọ títí, kí adé pẹ́ lórí kì í ṣe láti ìrandíran. Lẹ́yìn tí a bá gé koríko, tí koríko tútù mìíràn sì hù, tí a bá kó koríko tí a gé lára àwọn òkè wálé, o óo rí irun aguntan fi hun aṣọ, o óo sì lè fi owó tí o bá pa lórí àwọn ewúrẹ́ rẹ ra ilẹ̀. O óo rí omi wàrà ewúrẹ́ rẹ fún, tí o óo máa rí mu, ìwọ ati ìdílé rẹ, ati àwọn iranṣẹbinrin rẹ pẹlu. Àwọn eniyan burúkú a máa sá, nígbà tí ẹnikẹ́ni kò lé wọn, ṣugbọn olódodo a máa láyà bíi kinniun. Bí orílẹ̀-èdè kan bá dẹ́ṣẹ̀, léraléra ni wọ́n ó máa jọba, ṣugbọn bí orílẹ̀-èdè kan bá ní àwọn eniyan tí wọn ní òye ati ìmọ̀, yóo wà fún ìgbà pípẹ́. Talaka tí ń ni aláìní lára dàbí òjò líle tí ó ba nǹkan ọ̀gbìn jẹ́. Àwọn tí wọ́n kọ òfin sílẹ̀ ni wọ́n máa ń yin àwọn eniyan burúkú, ṣugbọn àwọn tí wọn ń pa òfin mọ́ máa ń dojú ìjà kọ wọ́n. Òye ìdájọ́ òdodo kò yé àwọn eniyan burúkú, ṣugbọn ó yé àwọn tí ń wá OLUWA yékéyéké. Talaka tí ń rìn pẹlu òtítọ́ inú sàn ju ọlọ́rọ̀ tí ń hùwà àgàbàgebè lọ. Ọlọ́gbọ́n ọmọ ni ọmọ tí ó pa òfin mọ́, ṣugbọn ẹni tí ń bá àwọn wọ̀bìà rìn, ń dójúti baba rẹ̀. Ẹni tí ó ń fi kún ọrọ̀ rẹ̀ nípa gbígba èlé ati èrè jíjẹ ní ọ̀nà èrú, ń kó ọrọ̀ náà jọ fún ẹni tí yóo ṣàánú àwọn talaka. Ẹni tí ó kọ etí dídi sí òfin Ọlọrun, adura rẹ̀ pàápàá yóo di ìríra sí Ọlọ́run. Ẹni tí ó ṣi olódodo lọ́nà lọ sinu ibi, yóo já sinu kòtò tí òun fúnrarẹ̀ gbẹ́ sílẹ̀, ṣugbọn aláìlẹ́bi eniyan yóo jogún ire. Ọlọ́rọ̀ gbọ́n lójú ara rẹ̀, ṣugbọn talaka tí ó gbọ́n yóo rídìí rẹ̀. Nígbà tí olódodo bá borí, àwọn eniyan á yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ṣugbọn nígbà tí ìkà bá dìde, àwọn eniyan á sá pamọ́. Ẹni tí ó bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kò ní ṣe rere, ṣugbọn ẹni tí ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tí ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀, yóo rí àánú gbà. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó ń bẹ̀rù OLUWA nígbà gbogbo, ṣugbọn ẹni tí ó sé ọkàn rẹ̀ le yóo bọ́ sinu ìyọnu. Ọba burúkú tí ó jọba lórí àwọn talaka, dàbí kinniun tí ń bú ramúramù, tabi ẹranko beari tí inú ń bí. Ìkà, aninilára ni olórí tí kò ní òye, ṣugbọn ẹ̀mí ẹni tí ó bá kórìíra à ń jèrè lọ́nà èrú yóo gùn. Bí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ẹnìkan bá ń da eniyan láàmú, yóo di ìsáǹsá ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, kí ẹnikẹ́ni má ṣe ràn án lọ́wọ́. Ẹni tí ń rìn pẹlu òtítọ́ inú yóo rí ìgbàlà, ṣugbọn ẹni tí ń rìn ségesège yóo ṣubú sinu kòtò. Ẹni tí ń ṣiṣẹ́ oko dáradára, yóo ní oúnjẹ pupọ, ṣugbọn ẹni tí ń fi àkókò rẹ̀ ṣòfò yóo di talaka. Olóòótọ́ yóo ní ibukun lọpọlọpọ, ṣugbọn ẹni tí ń kánjú àtilówó, kò ní lọ láìjìyà. Ojuṣaaju kò dára, sibẹ oúnjẹ lè mú kí eniyan ṣe ohun tí kò tọ́. Ahun a máa sáré ati ní ọrọ̀, láìmọ̀ pé òṣì ń bọ̀ wá ta òun. Ẹni tí ó bá eniyan wí, yóo rí ojurere níkẹyìn, ju ẹni tí ń pọ́n eniyan lọ. Ẹni tí ó ja ìyá tabi baba rẹ̀ lólè, tí ó ní, “Kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀”, ẹlẹgbẹ́ apanirun ni. Olójúkòkòrò eniyan a máa dá ìjà sílẹ̀, ṣugbọn ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA yóo ṣe rere. Òmùgọ̀ ni ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé ara rẹ̀, ẹni tí ń fi ọgbọ́n rìn yóo là. Ẹni tí ó ta talaka lọ́rẹ kò ní ṣe aláìní, ṣugbọn ẹni tí ó fojú pamọ́ fún wọn, yóo gba ègún. Nígbà tí àwọn eniyan burúkú bá dìde, àwọn eniyan á sá pamọ́, ṣugbọn nígbà tí wọ́n bá parun, olódodo á pọ̀ sí i. Ẹni tí à ń báwí tí ó ń ṣoríkunkun, yóo parun lójijì láìsí àtúnṣe. Nígbà tí olódodo bá di eniyan pataki, àwọn eniyan a máa yọ̀, ṣugbọn nígbà tí eniyan burúkú bá wà lórí oyè, àwọn eniyan a máa kérora. Ọlọ́gbọ́n ọmọ a máa mú inú baba rẹ̀ dùn, ṣugbọn ẹni tí ń tẹ̀lé aṣẹ́wó kiri, ń fi ọrọ̀ ara rẹ̀ ṣòfò. Ọba tí ó bá ń ṣe ìdájọ́ òdodo, a máa fìdí orílẹ̀-èdè múlẹ̀, ṣugbọn ọba onírìbá a máa dojú orílẹ̀-èdè bolẹ̀. Ẹni tí ó bá ń pọ́n aládùúgbò rẹ̀, ń dẹ àwọ̀n sílẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ̀. Eniyan burúkú bọ́ sinu àwọ̀n ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn olódodo lè kọrin, ó sì lè máa yọ̀. Olódodo a máa bìkítà fún ẹ̀tọ́ àwọn talaka, ṣugbọn àwọn eniyan burúkú kò ní òye irú rẹ̀. Àwọn ẹlẹ́gàn a máa dá rúkèrúdò sílẹ̀ láàrin ìlú, ṣugbọn àwọn ọlọ́gbọ́n a máa paná ibinu. Nígbà tí ọlọ́gbọ́n bá pe òmùgọ̀ lẹ́jọ́, ẹ̀rín ni òmùgọ̀ yóo máa fi rín, yóo máa pariwo, kò sì ní dákẹ́. Àwọn apànìyàn kórìíra olóòótọ́ inú, wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa á. Òmùgọ̀ eniyan a máa bínú, ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa mú sùúrù. Bí aláṣẹ bá ń fetí sí irọ́, gbogbo àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ yóo di eniyankeniyan. Ohun tí ó sọ talaka ati aninilára di ọ̀kan náà ni pé, OLUWA ló fún àwọn mejeeji ní ojú láti ríran. Ọba tí ó dájọ́ ẹ̀tọ́ fún talaka, ní a óo fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ títí. Pàṣán ati ìbáwí a máa kọ́ ọmọ lọ́gbọ́n, ọmọ tí a bá fi sílẹ̀ yóo dójúti ìyá rẹ̀. Nígbà tí eniyan burúkú bá wà lórí oyè, ẹ̀ṣẹ̀ a máa pọ̀ síi, ṣugbọn lójú olódodo ni wọn yóo ti ṣubú. Tọ́ ọmọ rẹ, yóo sì fún ọ ní ìsinmi, yóo sì mú inú rẹ dùn. Orílẹ̀-èdè tí kò bá ní ìfihàn láti ọ̀run, yóo dàrú, ṣugbọn ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ń pa òfin mọ́. Ọ̀rọ̀ ẹnu nìkan kò tó láti fi bá ẹrú wí, ó lè fi etí gbọ́ ṣugbọn kí ó má ṣe ohunkohun. Òmùgọ̀ nírètí ju ẹni tí yóo sọ̀rọ̀ sọ̀rọ̀, tí kò lè kó ara rẹ̀ ní ìjánu lọ. Bí eniyan bá kẹ́ ẹrú ní àkẹ́jù, yóo ya ìyàkuyà níkẹyìn. Ẹni tí inú ń bí a máa dá rògbòdìyàn sílẹ̀, onínúfùfù a sì máa ṣe ọpọlọpọ àṣìṣe. Ìgbéraga eniyan a máa rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀, ṣugbọn onírẹ̀lẹ̀ ọkàn yóo gba iyì. Ẹni tí ó ṣe alábàápín pẹlu olè kò fẹ́ràn ẹ̀mí ara rẹ̀, ó gbọ́ ọ̀rọ̀ ègún, ṣugbọn kò sọ fún ẹnikẹ́ni. Ìbẹ̀rù eniyan a máa di ìdẹkùn fún eniyan, ṣugbọn ẹni bá gbẹ́kẹ̀lé OLUWA yóo wà láìléwu. Ọ̀pọ̀ ń wá ojurere olórí, ṣugbọn OLUWA níí dáni ní ẹjọ́ òdodo. Olódodo a máa kórìíra alaiṣootọ, eniyan burúkú a sì kórìíra eniyan rere. Ọ̀rọ̀ Aguri, ọmọ Jake ará Masa nìyí: Ọkunrin yìí sọ fún Itieli ati Ukali pé, “Nítòótọ́ mo jẹ́ aláìmọ̀kan jùlọ ninu gbogbo eniyan, n kò ní òye tí ó yẹ kí eniyan ní. N kò tíì kọ́ ọgbọ́n, n kò sì ní ìmọ̀ Ẹni Mímọ́. Ta ló ti lọ sí ọ̀run rí, tí ó sì tún pada wá? Ta ló ti kó afẹ́fẹ́ jọ sí ọwọ́ rẹ̀? Ta ló ti fi aṣọ rẹ̀ di omi? Ta ló fi ìdí gbogbo òpin ayé múlẹ̀? Kí ni orúkọ olúwarẹ̀? Kí sì ni orúkọ ọmọ rẹ̀? Ṣé o mọ̀ ọ́n! Kò sí ọ̀rọ̀ Ọlọrun kankan tí ó ń yẹ̀, òun ni ààbò fún àwọn tí wọ́n wá ààbò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Má fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀, kí ó má baà bá ọ wí, kí o má baà di òpùrọ́.” Nǹkan meji ni mò ń tọrọ lọ́wọ́ rẹ, má ṣe fi wọ́n dù mí kí n tó kú. Jẹ́ kí ìwà èké ati irọ́ pípa jìnnà sí mi, má jẹ́ kí n talaka, má sì jẹ́ kí n di ọlọ́rọ̀, fún mi ní ìwọ̀nba oúnjẹ tí ó tó mi jẹ, kí n má baà yó tán, kí n sẹ́ ọ, kí n wí pé, “Ta ni ń jẹ́ OLUWA?” Má sì jẹ́ kí n tòṣì, kí n má baà jalè, kí n sì kó ẹ̀gbin bá orúkọ Ọlọrun. Má ba iranṣẹ jẹ́ lójú ọ̀gá rẹ̀, kí ó má baà gbé ọ ṣépè, kí o sì di ẹlẹ́bi. Àwọn kan wà tí wọn ń gbé baba wọn ṣépè, tí wọn kò sì súre fún ìyá wọn. Àwọn tí wọ́n mọ́ lójú ara wọn, ṣugbọn a kò tíì wẹ èérí wọn nù. Àwọn kan wà tí ojú wọ́n ga, lókè lókè ni ojú wọn wà. Àwọn kan wà tí eyín wọn dàbí idà, kìkì ọ̀bẹ ló kún èrìgì wọn, láti jẹ àwọn talaka run lórí ilẹ̀ ayé, ati láti pa àwọn aláìní run láàrin àwọn eniyan. Eṣúṣú bí ọmọbinrin meji, ó sì sọ àwọn mejeeji ni: “Mú wá, Mú wá.” Àwọn nǹkan pupọ wà tí kì í ní ìtẹ́lọ́rùn, wọ́n pọ̀ tí nǹkan kìí tó: isà òkú ati inú àgàn, ilẹ̀ tí ń pòùngbẹ omi ati iná, wọn kì í sọ pé, “Ó tó.” Ẹni tí ń fi baba rẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́, tí ó kọ̀ tí kò tẹríba fún ìyá rẹ̀, ẹyẹ ìwò àfonífojì ati àwọn igún ni yóo yọ ojú rẹ̀ jẹ. Àwọn nǹkankan wà tí ń jọ mí lójú, àwọn nǹkan mẹrin kò yé mi: ipa ẹyẹ idì ní ojú ọ̀run, ipa ejò lórí àpáta, ọ̀nà tí ọkọ̀ ń tọ̀ lójú òkun, ati nǹkan tí ń bẹ láàrin ọkunrin ati obinrin. Ìwà obinrin alágbèrè nìyí: bí ó bá ṣe àgbèrè tán, á ṣojú fúrú, á ní “N kò ṣe àìdára kankan.” Àwọn nǹkankan wà tíí mi ilẹ̀ tìtì, ọ̀pọ̀ nǹkan wà tí ilẹ̀ kò lè gbà mọ́ra: ẹrú tí ó jọba, òmùgọ̀ tí ó jẹun yó, obinrin tí ayé kórìíra tí ó wá rí ọkọ fẹ́, ati iranṣẹbinrin tí ó gba ọkọ mọ́ ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́. Àwọn nǹkan mẹrin kan wà tí wọ́n kéré ninu ayé, sibẹsibẹ wọ́n gbọ́n lọpọlọpọ: àwọn èèrà kò lágbára, ṣugbọn wọn a máa kó oúnjẹ wọn jọ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn. Àwọn ehoro ìgbẹ́ kò lágbára, sibẹsibẹ wọ́n ń kọ́ ilé sí pàlàpálá òkúta. Àwọn eṣú kò ní ọba, sibẹsibẹ wọ́n ń rìn ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Eniyan lè fi ọwọ́ mú aláǹgbá, sibẹsibẹ wọ́n pọ̀ ní ààfin ọba. Àwọn nǹkan mélòó kan wà tí ìrìn yẹ, àwọn nǹkan pọ̀ tí ìrìn ẹsẹ̀ wọn máa ń wu eniyan: Kinniun, alágbára jùlọ láàrin àwọn ẹranko, kì í sì í sá fún ẹnikẹ́ni. Àkùkọ gàgàrà ati ẹran òbúkọ, ati ọba tí ń yan níwájú àwọn eniyan rẹ̀. Bí o bá ti ń hùwà òmùgọ̀, tí ò ń gbé ara rẹ ga, tabi tí o tí ń gbèrò ibi, fi òpin sí i, kí o sì ronú. Bí a bá po wàrà pọ̀ títí, yóo di òrí àmọ́, bí ó bá pẹ́ tí a ti ń tẹ imú, imú yóo ṣẹ̀jẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ríru ibinu sókè, a máa mú ìjà wá! Èyí ni ọ̀rọ̀ Lemueli, ọba Masa, tí ìyá rẹ̀ kọ́ ọ: Ìwọ ni ọmọ mi, ọmọ bíbí inú mi, ìwọ ni ọmọ tí mo jẹ́jẹ̀ẹ́ bí. Má ṣe lo agbára rẹ lórí obinrin, má fi ọ̀nà rẹ lé àwọn tí wọn ń pa ọba run lọ́wọ́. Gbọ́, ìwọ Lemueli, ọba kò gbọdọ̀ máa mu ọtí, àwọn aláṣẹ kò sì gbọdọ̀ máa wá ọtí líle. Kí wọn má baà mu ún tán, kí wọn gbàgbé òfin, kí wọn sì yí ìdájọ́ ẹni tí ojú ń pọ́n po. Fún ẹni tí ń ṣègbé lọ ní ọtí mu, fún àwọn tí ọkàn wọ́n bàjẹ́ ní ọtí líle, jẹ́ kí wọn mu ún, kí wọn gbàgbé òṣì wọn, kí wọn má sì ranti ìnira wọn mọ́. Gba ẹjọ́ àwọn tí kò ní ẹnu ọ̀rọ̀ rò, ati ti àwọn tí a sọ di aláìní. Má dákẹ́, kí o ṣe ìdájọ́ òdodo, bá talaka ati aláìní gba ẹ̀tọ́ wọn. Ta ló lè rí iyawo tí ó ní ìwà rere fẹ́? Ó ṣọ̀wọ́n ju ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye lọ. Ọkọ rẹ̀ yóo fi tọkàntọkàn gbẹ́kẹ̀lé e, kò sì ní ṣaláì ní ohunkohun. Rere ni obinrin náà máa ń ṣe fún un kò ní ṣe é níbi, ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. A máa lọ wá irun aguntan ati òwú ìhunṣọ, a sì máa fi tayọ̀tayọ̀ hun aṣọ. Obinrin náà dàbí ọkọ̀ ojú omi oníṣòwò, tí ó ń mú oúnjẹ wálé láti ọ̀nà jíjìn réré. Ìdájí níí tií jí láti wá oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀, ati láti yan iṣẹ́ fún àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀. Bí ó bá rí ilẹ̀ oko, a yẹ̀ ẹ́ wò, a sì rà á, a sì fi èrè iṣẹ́ rẹ̀ gbin ọgbà àjàrà. A fi agbára fún ọ̀já mọ́nú, a sì tẹpá mọ́ṣẹ́. A máa mójútó ọjà tí ó ń tà, fìtílà rẹ̀ kì í sì í kú lóru. Ó fi ọwọ́ lé kẹ̀kẹ́ òwú, ó sì ń ran òwú. Ó lawọ́ sí àwọn talaka, a sì máa ran àwọn aláìní lọ́wọ́. Kì í bẹ̀rù nítorí ìdílé rẹ̀ nígbà òtútù, nítorí gbogbo wọn ni ó ti bá hun aṣọ tí ó móoru. A máa hun aṣọ ọlọ́nà a sì fi bo ibùsùn rẹ̀, òun náà á wọ aṣọ funfun dáradára ati ti elése àlùkò. Wọ́n dá ọkọ rẹ̀ mọ̀ lẹ́nu ibodè, nígbà tí ó bá jókòó pẹlu àwọn àgbààgbà ìlú. A máa hun aṣọ funfun, a sì tà wọ́n, a máa ta ọ̀já ìgbànú fún àwọn oníṣòwò. Agbára ati ọlá ni ó fi ń bora bí aṣọ, ó sì ní ìrètí ayọ̀ nípa ọjọ́ iwájú. Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ní ń jáde láti ẹnu rẹ̀, a sì máa kọ́ni ní ẹ̀kọ́ àánú. A máa ṣe ìtọ́jú ìdílé rẹ̀ dáradára, kì í sì í hùwà ọ̀lẹ. Àwọn ọmọ rẹ̀ a máa pè é ní ẹni ibukun, ọkọ rẹ̀ pẹlu a sì máa yìn ín pé, “Ọpọlọpọ obinrin ni wọ́n ti ṣe ribiribi, ṣugbọn ìwọ ta gbogbo wọn yọ.” Ẹ̀tàn ni ojú dáradára, asán sì ni ẹwà, obinrin tí ó bá bẹ̀rù OLUWA ni ó yẹ kí á yìn. Fún un ninu èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, jẹ́ kí wọn máa yìn ín lẹ́nu ibodè nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Ọ̀rọ̀ ọ̀jọ̀gbọ́n, ọmọ Dafidi, Ọba Jerusalẹmu nìyí. Asán ninu asán, bí ọ̀jọ̀gbọ́n ti wí, asán ninu asán, gbogbo rẹ̀ asán ni. Èrè kí ni eniyan ń jẹ ninu gbogbo làálàá rẹ̀, tí ó ń ṣe nílé ayé? Ìran kan ń kọjá lọ, òmíràn ń dé, ṣugbọn ayé wà títí laelae. Oòrùn ń yọ, oòrùn ń wọ̀, ó sì ń yára pada sí ibi tí ó ti yọ wá. Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ sí ìhà gúsù, ó sì ń yípo lọ sí ìhà àríwá. Yíyípo ni afẹ́fẹ́ ń yípo, a sì tún pada sí ibi tí ó ti wá. Inú òkun ni gbogbo odò tí ń ṣàn ń lọ, ṣugbọn òkun kò kún. Ibi tí àwọn odò ti ń ṣàn wá, ibẹ̀ ni wọ́n tún ṣàn pada lọ. Gbogbo nǹkan ní ń kó àárẹ̀ bá eniyan, ju bí ẹnu ti lè sọ lọ. Ìran kì í sú ojú, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ kì í kún etí. Ohun tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ náà ni yóo máa wà. Ohun tí a ti ṣe tẹ́lẹ̀ náà ni a óo tún máa ṣe, kò sí ohun titun kan ní ilé ayé. Ǹjẹ́ ohun kankan wà tí a lè tọ́ka sí pé: “Wò ó! Ohun titun nìyí.” Ó ti wà rí ní ìgbà àtijọ́. Kò sí ẹni tí ó ranti àwọn nǹkan àtijọ́ mọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni, kò sì ní sí ẹni tí yóo ranti àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la. Èmi ọ̀jọ̀gbọ́n yìí ti jẹ ọba lórí Israẹli, ní Jerusalẹmu. Mo fi tọkàntọkàn pinnu láti fi ọgbọ́n wádìí gbogbo ohun tí eniyan ń ṣe láyé. Làálàá lásán ni iṣẹ́ tí Ọlọrun fún ọmọ eniyan ṣe lórí ilẹ̀ ayé. Mo ti wo gbogbo nǹkan tí eniyan ń ṣe láyé, wò ó, asán ati ìmúlẹ̀mófo ni gbogbo rẹ̀. Ohun tí ó bá ti wọ́, ẹnìkan kò lè tọ́ ọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kò lè ka ohun tí kò bá sí. Mo wí lọ́kàn ara mi pé, “Mo ti kọ́ ọpọlọpọ ọgbọ́n, ju gbogbo àwọn tí wọ́n ti jọba ní Jerusalẹmu ṣáájú mi lọ. Mo ní ọpọlọpọ ìrírí tí ó kún fún ọgbọ́n ati ìmọ̀.” Mo pinnu lọ́kàn mi láti mọ ohun tí ọgbọ́n jẹ́, ati láti mọ ohun tí ìwà wèrè ati ìwà òmùgọ̀ jẹ́. Mo wá wòye pé èyí pàápàá jẹ́ ìmúlẹ̀mófo. Nítorí pé ọpọlọpọ ọgbọ́n a máa mú ọpọlọpọ ìbànújẹ́ wá, ẹni tí ń fi ìmọ̀ kún ìmọ̀ rẹ̀, ó ń fi kún ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀ ni. Mo wí ninu ọkàn mi pé, n óo dán ìgbádùn wò; n óo gbádùn ara mi, ṣugbọn, èyí pàápàá, asán ni. Mo ní, “Ẹ̀rín rínrín dàbí ìwà wèrè, ìgbádùn kò sì jámọ́ nǹkankan fún eniyan.” Mo ronú bí mo ti ṣe lè fi waini mú inú ara mi dùn, ṣugbọn tí kò ní pa ọgbọ́n mọ́ mi ninu; mo tún ronú ohun tí mo lè ṣe pẹlu ìwà òmùgọ̀ títí tí n óo fi lè rí ohun tí ó dára fún ọmọ eniyan láti máa ṣe láyé níwọ̀n àkókò díẹ̀ tí Ọlọrun fún wọn láti gbé lórí ilẹ̀ ayé. Mo gbé àwọn nǹkan ribiribi ṣe: mo kọ́ ilé, mo gbin ọgbà àjàrà fún ara mi. Mo ní ọpọlọpọ ọgbà ati àgbàlá, mo sì gbin oríṣìíríṣìí igi eléso sinu wọn. Mo gbẹ́ adágún omi láti máa bomirin àwọn igi tí mo gbìn. Mo ra ọpọlọpọ ẹrukunrin ati ẹrubinrin, mo sì ní àwọn ọmọ ẹrú tí wọn bí ninu ilé mi, mo ní ọpọlọpọ agbo mààlúù ati agbo ẹran, ju àwọn tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu ṣáájú mi lọ. Mo kó fadaka ati wúrà jọ fún ara mi; mo gba ìṣúra àwọn ọba ati ti àwọn agbègbè ìjọba mi. Mo ní àwọn akọrin lọkunrin ati lobinrin, mo sì ní ọpọlọpọ obinrin tíí mú inú ọkunrin dùn. Nítorí náà, mo di eniyan ńlá, mo ju ẹnikẹ́ni tí ó ti wà ní Jerusalẹmu ṣáájú mi lọ, ọgbọ́n sì tún wà lórí mi. Kò sí ohunkohun tí ojú mi fẹ́ rí tí n kò fún un. Kò sí ìgbádùn kan tí n kò fi tẹ́ ara mi lọ́rùn, nítorí mo jẹ ìgbádùn gbogbo ohun tí mo ṣe. Èrè gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ mi nìyí. Lẹ́yìn náà, ni mo ro gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ mi, ati gbogbo làálàá mi lórí rẹ̀; sibẹ: mo wòye pé asán ati ìmúlẹ̀mófo ni gbogbo rẹ̀, kò sì sí èrè kankan láyé. Nítorí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí ronú nípa ìwà ọlọ́gbọ́n, ìwà wèrè ati ìwà òmùgọ̀. Mo rò ó pé kí ni ẹnìkan lè ṣe lẹ́yìn èyí tí ọba ti ṣe ṣáájú rẹ̀? Mo wá rí i pé bí ìmọ́lẹ̀ ti dára ju òkùnkùn lọ ni ọgbọ́n dára ju ìwà wèrè lọ. Ọlọ́gbọ́n ní ojú lágbárí, ṣugbọn ninu òkùnkùn ni òmùgọ̀ ń rìn. Sibẹ mo rí i pé, nǹkankan náà ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn. Nígbà náà ni mo sọ lọ́kàn ara mi pé, “Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí òmùgọ̀ ni yóo ṣẹlẹ̀ sí èmi náà. Kí wá ni ìwúlò ọgbọ́n mi?” Mo sọ fún ara mi pé, asán ni eléyìí pẹlu. Nítorí pé àtọlọ́gbọ́n, àtòmùgọ̀, kò sẹ́ni tíí ranti wọn pẹ́ lọ títí. Nítorí pé ní ọjọ́ iwájú, gbogbo wọn yóo di ẹni ìgbàgbé patapata. Ẹ wo bí ọlọ́gbọ́n ti í kú bí òmùgọ̀. Nítorí náà mo kórìíra ayé, nítorí gbogbo nǹkan tí ń ṣẹlẹ̀ láyé ń bà mí ninu jẹ́, nítorí pé asán ati ìmúlẹ̀mófo ni gbogbo wọn. Mo kórìíra làálàá tí mo ti ṣe láyé, nígbà tí mo rí i pé n óo fi í sílẹ̀ fún ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi. Ta ni ó sì mọ̀ bóyá ọlọ́gbọ́n ni yóo jẹ́, tabi òmùgọ̀ eniyan? Sibẹsibẹ òun ni yóo jọ̀gá lórí gbogbo ohun tí mo fi ọgbọ́n mi kó jọ láyé yìí. Asán ni èyí pẹlu. Nítorí náà mo pada kábàámọ̀ lórí gbogbo ohun tí mo fi làálàá kójọ. Nítorí pé nígbà mìíràn ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́ pẹlu ọgbọ́n, ìmọ̀ ati òye yóo fi gbogbo rẹ̀ sílẹ̀ fún ẹni tí kò ṣe làálàá fún wọn. Asán ni èyí pẹlu, nǹkan burúkú sì ni. Kí ni eniyan rí gbà ninu gbogbo làálàá rẹ̀, kí sì ni èrè eniyan lórí akitiyan, ati iṣẹ́ tí ó ń ṣe láyé. Nítorí gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ kún fún ìrora, iṣẹ́ rẹ̀ sì jẹ́ ìbànújẹ́ fún un. Ọkàn rẹ̀ kì í balẹ̀ lóru, asán ni èyí pẹlu. Kò sí ohun tí ó dára fún eniyan ju kí ó jẹun kí ó sì máa gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ lọ. Sibẹ mo rí i pé ọwọ́ Ọlọrun ni èyí tún ti ń wá. Nítorí láìsí àṣẹ rẹ̀, ta ló lè jẹun, tabi kí ó gbádùn ohunkohun. Ọlọrun a máa fún ẹni tí ó bá ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní ọgbọ́n, ìmọ̀, ati inú dídùn; ṣugbọn iṣẹ́ àtikójọ ati àtitòjọ níí fún ẹlẹ́ṣẹ̀, kí wọ́n lè fún àwọn tí ó bá wu Ọlọrun. Asán ati ìmúlẹ̀mófo ni èyí pàápàá. Gbogbo nǹkan láyé yìí ló ní àkókò ati ìgbà tirẹ̀: àkókò bíbí wà, àkókò kíkú sì wà; àkókò gbígbìn wà, àkókò kíkórè ohun tí a gbìn sì wà. Àkókò pípa wà, àkókò wíwòsàn sì wà, àkókò wíwó lulẹ̀ wà, àkókò kíkọ́ sì wà. Àkókò ẹkún wà, àkókò ẹ̀rín sì wà; àkókò ọ̀fọ̀ wà, àkókò ijó sì wà. Àkókò fífọ́n òkúta ká wà, àkókò kíkó òkúta jọ sì wà; àkókò ìkónimọ́ra wà, àkókò àìkónimọ́ra sì wà. Àkókò wíwá nǹkan wà, àkókò sísọ nǹkan nù wà; àkókò fífi nǹkan pamọ́ wà, àkókò dída nǹkan nù sì wà. Àkókò fífa nǹkan ya wà, àkókò rírán nǹkan pọ̀ sì wà; àkókò dídákẹ́ wà, àkókò ọ̀rọ̀ sísọ sì wà. Àkókò láti fi ìfẹ́ hàn wà àkókò láti kórìíra sì wà; àkókò ogun wà, àkókò alaafia sì wà. Kí ni èrè làálàá òṣìṣẹ́? Mo ti mọ ẹrù ńlá tí Ọlọrun dì ru ọmọ eniyan. Ó ṣe ohun gbogbo dáradára, ní àkókò rẹ̀. Ó fi ayérayé sí ọkàn eniyan, sibẹ, ẹnikẹ́ni kò lè rídìí ohun tí Ọlọrun ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. Mo mọ̀ pé kò sí ohun tí ó yẹ wọ́n ju pé kí inú wọn máa dùn, kí wọ́n sì máa ṣe rere ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn; ati pé ẹ̀bùn Ọlọrun ni pé kí olukuluku jẹ, kí ó mu, kí ó sì gbádùn lẹ́yìn làálàá rẹ̀. Mo mọ̀ pé gbogbo ohun tí Ọlọrun ṣe, yóo wà títí lae. Kò sí ohun tí ẹ̀dá lè fi kún un, tabi tí ẹ̀dá lè yọ kúrò níbẹ̀, Ọlọrun ni ó dá a bẹ́ẹ̀ kí eniyan lè máa bẹ̀rù rẹ̀. Ohunkohun tí ó wà, ó ti wà tẹ́lẹ̀, èyí tí yóo sì tún wà, òun pàápàá ti wà rí; Ọlọrun yóo ṣe ìwádìí gbogbo ohun tí ó ti kọjá. Mo rí i pé ninu ayé yìí ibi tí ó yẹ kí ìdájọ́ òtítọ́ ati òdodo wà ibẹ̀ gan-an ni ìwà ìkà wà. Mo wí ní ọkàn ara mi pé, Ọlọrun yóo dájọ́ fún olódodo ati fún eniyan burúkú; nítorí ó ti yan àkókò fún ohun gbogbo ati fún iṣẹ́ gbogbo. Mo wí ní ọkàn ara mi pé Ọlọrun ń dán àwọn ọmọ eniyan wò, láti fihàn wọ́n pé wọn kò yàtọ̀ sí ẹranko; nítorí kò sí ìyàtọ̀ láàrin òpin eniyan ati ti ẹranko. Bí eniyan ṣe ń kú, ni ẹranko ṣe ń kú. Èémí kan náà ni wọ́n ń mí; eniyan kò ní anfaani kankan ju ẹranko lọ; nítorí pé asán ni ohun gbogbo. Ibìkan náà ni gbogbo wọn ń lọ; inú erùpẹ̀ ni gbogbo wọn ti wá, inú erùpẹ̀ ni wọn yóo sì pada sí. Ta ló mọ̀ dájúdájú, pé ẹ̀mí eniyan a máa gòkè lọ sọ́run; tí ti ẹranko sì ń sọ̀kalẹ̀ lọ sinu ilẹ̀? Nítorí náà, mo rí i pé kò sí ohun tí ó dára, ju pé kí eniyan jẹ ìgbádùn iṣẹ́ rẹ̀ lọ, nítorí ìpín tirẹ̀ ni. Ta ló lè dá eniyan pada sáyé, kí ó wá rí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí ó bá ti kú? Mo tún rí i bí àwọn eniyan tí ń ni ẹlòmíràn lára láyé. Wò ó! Omi ń bọ́ lójú àwọn tí à ń ni lára, Kò sì sí ẹnìkan tí yóo tù wọ́n ninu. Ọ̀dọ̀ àwọn tí ń ni wọ́n lára ni agbára kọ̀dí sí, kò sì sí ẹni tí yóo tu àwọn tí à ń ni lára ninu. Mo wá rò ó pé, àwọn òkú, tí wọ́n ti kú, ṣe oríire ju àwọn alààyè tí wọ́n ṣì wà láàyè lọ. Ṣugbọn ti ẹni tí wọn kò tíì bí rárá, sàn ju ti àwọn mejeeji lọ, nítorí kò tíì rí iṣẹ́ ibi tí àwọn ọmọ aráyé ń ṣe. Mo rí i pé gbogbo làálàá tí eniyan ń ṣe ati gbogbo akitiyan rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀, ó ń ṣe é nítorí pé eniyan ń jowú aládùúgbò rẹ̀ ni. Asán ati ìmúlẹ̀mófo ni èyí pàápàá. Òmùgọ̀ eniyan níí káwọ́ gbera, tíí fi ebi pa ara rẹ̀ dójú ikú. Ó sàn kí eniyan ní nǹkan díẹ̀ pẹlu ìbàlẹ̀ àyà ju pé kí ó ní ọpọlọpọ, pẹlu làálàá ati ìmúlẹ̀mófo lọ. Mo tún rí ohun asán kan láyé: Ọkunrin kan wà tí kò ní ẹnìkan, kò lọ́mọ, kò lárá, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìyekan, sibẹsibẹ làálàá rẹ̀ kò lópin, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìtẹ́lọ́rùn ninu ọrọ̀ rẹ̀. Kò fijọ́ kan bi ara rẹ̀ léèrè rí pé, “Ta ni mò ń ṣe làálàá yìí fún tí mo sì ń fi ìgbádùn du ara mi?” Asán ni èyí pàápàá ati ìmúlẹ̀mófo. Eniyan meji sàn ju ẹnìkan ṣoṣo lọ, nítorí wọn yóo lè jọ ṣiṣẹ́, èrè wọn yóo sì pọ̀. Bí ọ̀kan bá ṣubú, ekeji yóo gbé e dìde. Ṣugbọn ẹni tí ó dá wà gbé! Nítorí nígbà tí ó bá ṣubú kò ní sí ẹni tí yóo gbé e dìde. Bẹ́ẹ̀ sì tún ni, bí eniyan meji bá sùn pọ̀, wọn yóo fi ooru mú ara wọn ṣugbọn báwo ni ẹnìkan ṣe lè fi ooru mú ara rẹ̀? Ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo ni eniyan kan lè dojú ìjà kọ, nítorí pé eniyan meji lè gba ara wọn kalẹ̀. Okùn onípọn mẹta kò lè ṣe é já bọ̀rọ̀. Ọlọ́gbọ́n ọdọmọde tí ó jẹ́ talaka, sàn ju òmùgọ̀ àgbàlagbà ọba, tí kò jẹ́ gba ìmọ̀ràn lọ, kì báà jẹ́ pé láti ọgbà ẹ̀wọ̀n ni òmùgọ̀ ọba náà ti bọ́ sórí ìtẹ́, tabi pé láti inú ìran talaka ni a ti bí i. Mo rí gbogbo alààyè tí ń rìn kiri láyé ati ọdọmọde náà tí yóo gba ipò ọba. Àwọn eniyan tí ó jọba lé lórí pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní òǹkà; sibẹ, àwọn ìran tí ó bá dé lẹ́yìn kò ní máa yọ̀ nítorí rẹ̀. Dájúdájú asán ati ìmúlẹ̀mófo ni èyí. Ṣọ́ra, nígbà tí o bá lọ sí ilé Ọlọrun, ó sàn kí o lọ máa kẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀ ju pé kí o lọ máa rúbọ bí àwọn aṣiwèrè tí ń ṣe, tí wọn kò sì mọ̀ pé nǹkan burúkú ni àwọn ń ṣe. Má fi ẹnu rẹ sọ ìsọkúsọ, má sì kánjú sọ̀rọ̀ níwájú Ọlọrun, nítorí Ọlọrun ń bẹ lọ́run ìwọ sì wà láyé, nítorí náà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ mọ níwọ̀n. Ọpọlọpọ àkóléyà ní ń mú kí eniyan máa lá àlákálàá, ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ni eniyan sì fi ń mọ òmùgọ̀. Bí o bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Ọlọrun, má fi falẹ̀, tètè san án, nítorí kò ní inú dídùn sí àwọn òmùgọ̀. Ó sàn kí o má jẹ́ ẹ̀jẹ́ rárá ju pé kí o jẹ́ ẹ̀jẹ́ kí o má mú un ṣẹ lọ. Má jẹ́ kí ẹnu rẹ mú ọ dẹ́ṣẹ̀, kí o má baà lọ máa yí ohùn pada lọ́dọ̀ iranṣẹ Ọlọrun pé, èèṣì ló ṣe. Má jẹ́ kí Ọlọrun bínú sí ọ, kí ó má baà pa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ run. Nígbà tí àlá bá pọ̀ ọ̀rọ̀ náà yóo pọ̀. Ṣugbọn pataki ni pé, ǹjẹ́ o tilẹ̀ bẹ̀rù Ọlọrun? Bí o bá wà ní agbègbè tí wọ́n ti ń pọ́n talaka lójú, tí kò sì sí ìdájọ́ òdodo ati ẹ̀tọ́, má jẹ́ kí èyí yà ọ́ lẹ́nu. Nítorí ẹni tí ó ga ju ọ̀gá àgbà lọ ń ṣọ́ ọ̀gá àgbà. Ẹni tó tún ga ju àwọn náà lọ tún ń ṣọ́ gbogbo wọn. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, anfaani ni ilẹ̀ tí à ń dáko sí jẹ́ fún ọba. Kò sí iye tó lè tẹ́ ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ owó lọ́rùn; bákan náà ni ẹni tí ó bá fẹ́ràn ọrọ̀, kò sí iye tí ó lè jẹ lérè tí yóo tẹ́ ẹ lọ́rùn. Asán ni èyí pẹlu. Bí ọrọ̀ bá ti ń pọ̀ sí, bẹ́ẹ̀ ni iye àwọn tí yóo máa lò ó yóo máa pọ̀ sí i. Kò sì sí èrè tí ọlọ́rọ̀ yìí ní ju pé ó fi ojú rí ọrọ̀ rẹ̀ lọ. Oorun dídùn ni oorun alágbàṣe, kì báà yó, kì báà má yó; ṣugbọn ìrònú ọrọ̀ kì í jẹ́ kí ọlọ́rọ̀ sùn lóru. Nǹkankan ń ṣẹlẹ̀, tí ó burú, tí mo ṣàkíyèsí láyé yìí, àwọn eniyan a máa kó ọrọ̀ jọ fún ìpalára ara wọn. Àdáwọ́lé wọn lè yí wọn lọ́wọ́, wọ́n sì lè fi bẹ́ẹ̀ pàdánù ọrọ̀ wọn, tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní lè rí nǹkankan fi sílẹ̀ fún àwọn ọmọ wọn. Bí eniyan ti wáyé níhòòhò láìmú nǹkankan lọ́wọ́ wá bẹ́ẹ̀ ni yóo pada, láìmú nǹkankan lọ́wọ́ lọ, bí èrè làálàá tí a ṣe láyé. Nǹkan burúkú gan-an ni èyí pàápàá jẹ́; pé bí a ṣe wá bẹ́ẹ̀ ni a óo ṣe lọ. Tabi èrè wo ni ó wà ninu pé asán ati ìmúlẹ̀mófo ni gbogbo làálàá wa láyé. Ninu òkùnkùn, ati ìbànújẹ́ ni a ti ń lo ìgbésí ayé wa, pẹlu ọpọlọpọ ìyọnu, àìsàn ati ibinu. Wò ó! Ohun tí mo rí pé ó dára jù, tí ó sì yẹ, ni pé kí eniyan jẹ, kí ó mu, kí ó sì gbádùn gbogbo làálàá tí ó ń ṣe láyé, ní ìwọ̀nba ọjọ́ tí Ọlọrun fún un, nítorí èyí ni ìpín rẹ̀. Gbogbo ẹni tí Ọlọrun bá fún ní ọrọ̀ ati ohun ìní, ati agbára láti gbádùn wọn, ati láti gba ìpín rẹ̀ kí ó sì láyọ̀ ninu iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ẹ̀bùn Ọlọrun ni. Kò ní ranti iye ọjọ́ ayé rẹ̀ nítorí pé, Ọlọrun ti fi ayọ̀ kún ọkàn rẹ̀. Mo tún rí nǹkankan tí ó burú nílé ayé. Ó sì wọ ọmọ eniyan lọ́rùn pupọ. Ẹni tí Ọlọrun fún ní ọrọ̀, ohun ìní ati iyì, tí ó ní ohun gbogbo tí ó fẹ́; sibẹsibẹ Ọlọrun kò jẹ́ kí ó gbádùn rẹ̀, ṣugbọn àjèjì ni ó ń gbádùn rẹ̀. Asán ni èyí, ìpọ́njú ńlá sì ni. Bí ẹnìkan bá bí ọgọrun-un ọmọ, tí ó sì gbé ọpọlọpọ ọdún láyé, ṣugbọn tí kò gbádùn àwọn ohun tí ó dára láyé, tí wọn kò sì sin òkú rẹ̀, ọmọ tí a bí lókùú sàn jù ú lọ. Nítorí òkúmọ yìí wá sinu asán, ó sì pada sinu òkùnkùn. Òkùnkùn bo orúkọ rẹ̀, ẹnìkan kò sì ranti rẹ̀ mọ́. Kò rí oòrùn rí, kò sì mọ nǹkankan, sibẹsibẹ ó ní ìsinmi; nítorí náà ó sàn ju ẹni tí ó bí ọgọrun-un ọmọ tí ó kú láìrí ẹni sin òkú rẹ̀ lọ. Bí ó tilẹ̀ gbé ẹgbaa (2,000) ọdún láyé kí ó tó kú, tí kò sì gbádùn ohun rere kankan, ibìkan náà ni gbogbo wọn ń pada lọ. Gbogbo làálàá tí eniyan ń ṣe, nítorí àtijẹun ni, sibẹsibẹ oúnjẹ kì í yó ni. Kí ni anfaani tí ọlọ́gbọ́n ní tí ó fi ju òmùgọ̀ lọ? Kí sì ni anfaani tí talaka rí ninu pé ó mọ̀ ọ́n ṣe ní àwùjọ eniyan. Ó sàn kí ojú ẹni rí nǹkan, ju kí á máa fi ọkàn lépa rẹ̀ lọ. Asán ati ìmúlẹ̀mófo ni èyí pẹlu. Ohunkohun tí ó bá ti wà, ó ti ní orúkọ tẹ́lẹ̀, a sì ti mọ ẹ̀dá eniyan, pé eniyan kò lè bá ẹni tí ó lágbára jù ú lọ jà. Asán a máa pọ̀ ninu ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀; kì í sì í ṣe eniyan ní anfaani. Ta ni ó mọ ohun tí ó dára fún eniyan láàrin ìgbà kúkúrú, tí kò ní ìtumọ̀, tí ó níí gbé láyé, àkókò tí ó dàbí òjìji tí ó ń kọjá lọ. Ta ló mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ láyé lẹ́yìn òun, lẹ́yìn tí ó bá ti kú tán? Orúkọ rere dára ju òróró olówó iyebíye lọ, ọjọ́ ikú sì dára ju ọjọ́ ìbí lọ. Ó dára láti lọ sí ilé àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ju ati lọ sí ibi àsè lọ, nítorí pé àwọn alààyè gbọdọ̀ máa rán ara wọn létí pé ikú ni òpin gbogbo eniyan. Gbogbo alààyè ni wọ́n gbọdọ̀ máa fi èyí sọ́kàn. Ìbànújẹ́ dára ju ẹ̀rín lọ; lóòótọ́ ó lè mú kí ojú fàro, ṣugbọn a máa mú ayọ̀ bá ọkàn. Ọkàn ọlọ́gbọ́n wà ní ilé àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, ṣugbọn ọkàn òmùgọ̀ wà ní ibi ìgbádùn. Ó dára kí eniyan fetí sí ìbáwí ọlọ́gbọ́n, ju láti máa gbọ́ orin ìyìn àwọn òmùgọ̀ lọ. Bí ẹ̀gún ṣe máa ń ta ninu iná, lábẹ́ ìkòkò, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀rín òmùgọ̀ rí. Asán ni èyí pẹlu. Dájúdájú, ìwà ìrẹ́jẹ a máa mú kí ọlọ́gbọ́n eniyan dàbí òmùgọ̀, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ a sì máa ra eniyan níyè. Òpin nǹkan sàn ju ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ, sùúrù sì dára ju ìwà ìgbéraga lọ. Má máa yára bínú, nítorí àyà òmùgọ̀ ni ibinu dì sí. Má máa bèèrè pé, “Kí ló dé tí ìgbà àtijọ́ fi dára ju ti ìsinsìnyìí lọ?” Irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀ kò mọ́gbọ́n lọ́wọ́. Ọgbọ́n dára bí ogún, a máa ṣe gbogbo eniyan ní anfaani. Nítorí pé bí ọgbọ́n ṣe jẹ́ ààbò, bẹ́ẹ̀ ni owó náà jẹ́ ààbò; anfaani ìmọ̀ ni pé, ọgbọ́n a máa dáàbò bo ọlọ́gbọ́n. Ẹ kíyèsí ọgbọ́n Ọlọrun, nítorí pé, ta ló lè tọ́ ohun tí ó bá dá ní wíwọ́? Máa yọ̀ nígbà tí ó bá dára fún ọ, ṣugbọn nígbà tí nǹkan kò bá dára, máa ranti pé Ọlọrun ló ṣe mejeeji. Nítorí náà, eniyan kò lè mọ ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la. Ninu gbogbo ìgbé-ayé asán mi, mo ti rí àwọn nǹkan wọnyi: Mo ti rí olódodo tí ó ṣègbé ninu òdodo rẹ̀, mo sì ti rí eniyan burúkú tí ẹ̀mí rẹ̀ gùn, pẹlu bí ó ti ń ṣe ibi. Má jẹ́ kí òdodo rẹ pọ̀ jù, má sì gbọ́n ní àgbọ́njù; kí ni o fẹ́ pa ara rẹ fún? Má ṣe burúkú jù, má sì jẹ́ òmùgọ̀. Ki ni o fẹ́ pa ara rẹ lọ́jọ́ àìpé fún? Di ekinni mú ṣinṣin, má sì jẹ́ kí ekeji bọ́ lọ́wọ́ rẹ; nítorí ẹni tí ó bá bẹ̀rù Ọlọrun yóo ní ìlọsíwájú. Ọgbọ́n yóo mú ọlọ́gbọ́n lágbára ju ọba mẹ́wàá lọ láàrin ìlú. Kò sí olódodo kan láyé tí ń ṣe rere, tí kò lẹ́ṣẹ̀. Má máa fetí sí gbogbo nǹkan tí àwọn eniyan bá wí, kí o má baà gbọ́ pé iranṣẹ rẹ kan ń bú ọ. Ìwọ náà mọ̀ ní ọkàn rẹ pé, ní ọpọlọpọ ìgbà ni ìwọ náà ti bú eniyan rí. Gbogbo nǹkan wọnyi ni mo ti fi ọgbọ́n wádìí. Mo sọ ninu ara mi pé, “Mo fẹ́ gbọ́n,” ṣugbọn ọgbọ́n jìnnà sí mi. Ta ló lè ṣe àwárí ohun tó jìnnà gbáà, tí ó jinlẹ̀ gan-an? Mo tún pinnu láti kẹ́kọ̀ọ́, láti ṣe ìwádìí, ati láti wá ọgbọ́n, kí n mọ gbogbo nǹkan, ati ibi tí ń bẹ ninu ìwà òmùgọ̀, ati àìlóye tí ó wà ninu ìwà wèrè. Mo rí i pé, nǹkankan wà tí ó burú ju ikú lọ: òun ni obinrin oníṣekúṣe. Ọkàn rẹ̀ dàbí tàkúté ati àwọ̀n, tí ọwọ́ rẹ̀ dàbí ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀. Ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọrun kò ní bọ́ sọ́wọ́ rẹ̀, ṣugbọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo kó sinu tàkúté rẹ̀. Ohun tí mo rí nìyí, lẹ́yìn tí mo farabalẹ̀ ṣe ìwádìí pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, òun ni mò ń rò nígbà gbogbo, sibẹ, ó ṣì ń rú mi lójú: Láàrin ẹgbẹrun ọkunrin a lè rí ẹnìkan ṣoṣo tí ó jẹ́ eniyan rere, ṣugbọn ninu gbogbo àwọn obinrin, kò sí ẹnìkan. Ẹ̀kọ́ tí mo rí kọ́ ni pé rere ni Ọlọrun dá eniyan, ṣugbọn àwọn ni wọ́n wá oríṣìíríṣìí ọ̀nà àrékérekè fún ara wọn. Ta ló dàbí ọlọ́gbọ́n? Ta ló sì mọ ìtumọ̀ nǹkan? Ọgbọ́n ní ń mú kí ojú ọlọ́gbọ́n máa dán, á mú kí ó tújúká kí ó gbàgbé ìṣòro. Pa òfin ọba mọ́, má sì fi ìwàǹwára jẹ́jẹ̀ẹ́ níwájú Ọlọrun. Tètè kúrò níwájú ọba, má sì pẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí ọ̀rọ̀ bá ń di ibinu, nítorí pé ohun tí ó bá wù ú ló lè ṣe. Nítorí pé ohun tí ọba bá sọ ni abẹ gé. Bí ọba bá ṣe nǹkan, ta ló tó yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ wò? Ẹni tí ó bá ń pa òfin mọ́ kò ní rí ibi; ọlọ́gbọ́n mọ àkókò ati ọ̀nà tí ó yẹ láti gbà ṣe nǹkan. Gbogbo nǹkan ló ní àkókò ati ìgbà tirẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wahala wọ ẹ̀dá lọ́rùn. Ẹnikẹ́ni kò mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la; ta ló lè sọ fún eniyan bí yóo ṣe ṣẹlẹ̀? Kò sí ẹni tí ó lágbára láti dá ẹ̀mí dúró, tabi láti yí ọjọ́ ikú pada, gbèsè ni ikú, kò sí ẹni tí kò ní san án; ìwà ibi àwọn tí ń ṣe ibi kò sì le gbà wọ́n sílẹ̀. Nígbà tí mo fi tọkàntọkàn pinnu láti ṣàkíyèsí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ nílé ayé, mo rí i pé ọpọlọpọ eniyan ní ń lo agbára wọn lórí àwọn ẹlòmíràn sí ìpalára ara wọn. Mo rí àwọn ẹni ibi tí a sin sí ibojì. Nígbà ayé wọn, wọn a ti máa ṣe wọlé-wọ̀de ní ibi mímọ́, àwọn eniyan a sì máa yìn wọ́n, ní ìlú tí wọn tí ń ṣe ibi. Asán ni èyí pẹlu. Nítorí pé wọn kì í tètè dá ẹjọ́ àwọn ẹni ibi, ni ọkàn ọmọ eniyan fi kún fún ìwà ibi. Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ tilẹ̀ ṣe ibi ní ọpọlọpọ ìgbà tí ọjọ́ rẹ̀ sì gùn, sibẹsibẹ mo mọ̀ pé yóo dára fún àwọn tí ó bẹ̀rù Ọlọrun. Ṣugbọn kò ní dára fún ẹni ibi, bẹ́ẹ̀ sì ni ọjọ́ rẹ̀ kò ní gùn bí òjìji, nítorí kò bẹ̀rù Ọlọrun. Ohun asán kan tún wà tí ń ṣẹlẹ̀ nílé ayé yìí, a rí àwọn olódodo tí wọn ń jẹ ìyà àwọn eniyan burúkú, tí eniyan burúkú sì ń gba èrè olódodo, asán ni èyí pẹlu. Ìmọ̀ràn mi ni pé, kí eniyan máa gbádùn, nítorí kò sí ire kan tí ọmọ eniyan tún ń ṣe láyé ju pé kí ó jẹ, kí ó mu, kí ó sì gbádùn lọ; nítorí èyí ni yóo máa bá a lọ ní gbogbo ọjọ́ tí Ọlọrun fún un láyé. Nígbà tí mo fi tọkàntọkàn pinnu láti wá ọgbọ́n ati láti wo iṣẹ́ tí wọn ń ṣe ní ayé, bí eniyan kì í tíí fi ojú ba oorun tọ̀sán-tòru, mo wá rí gbogbo iṣẹ́ Ọlọrun pé, kò sí ẹni tí ó lè rí ìdí iṣẹ́ tí ó ń ṣe láyé. Kò sí bí eniyan ti lè ṣe làálàá tó, kò lè rí ìdí rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ń sọ pé àwọn mọ iṣẹ́ OLUWA, sibẹsibẹ wọn kò lè rí ìdí rẹ̀. Gbogbo nǹkan wọnyi ni mo fi sọ́kàn. Mo yẹ gbogbo rẹ̀ wò, bí ó ti jẹ́ pé ọwọ́ Ọlọrun ni àwọn olódodo, àwọn ọlọ́gbọ́n, ati gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ wọn wà. Bí ti ìfẹ́ ni, bí ti ìkórìíra ni, ẹnìkan kò mọ̀. Asán ni gbogbo ohun tí ó wà níwájú wọn. Nítorí nǹkankan náà ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn: ati olódodo ati ẹlẹ́ṣẹ̀, ati eniyan rere ati eniyan burúkú, ati ẹni mímọ́, ati ẹni tí kò mọ́, ati ẹni tí ń rúbọ ati ẹni tí kì í rú. Bí eniyan rere ti rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹlẹ́ṣẹ̀ náà rí. Bákan náà ni ẹni tí ń búra ati ẹni tí ó takété sì ìbúra. Nǹkankan tí ó burú, ninu àwọn nǹkan tí ń ṣẹlẹ̀ nílé ayé ni pé, ìpín kan náà ni gbogbo ọmọ aráyé ní, ọkàn gbogbo eniyan kún fún ibi, ìwà wèrè sì wà lọ́kàn wọn; lẹ́yìn náà, wọn a sì kú. Ṣugbọn ìrètí ń bẹ fún ẹni tí ó wà láàyè, nítorí pé ààyè ajá wúlò ju òkú kinniun lọ. Nítorí alààyè mọ̀ pé òun óo kú, ṣugbọn òkú kò mọ nǹkankan mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní èrè kan mọ́, a kò sì ní ranti wọn mọ́. Ìfẹ́, ati ìkórìíra, ati ìlara wọn ti parun, wọn kò sì ní ìpín kankan mọ́ laelae ninu ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nílé ayé. Máa lọ fi tayọ̀tayọ̀ jẹ oúnjẹ rẹ, sì máa mu ọtí waini rẹ pẹlu ìdùnnú, nítorí Ọlọrun ti fi ọwọ́ sí ohun tí ò ń ṣe. Máa wọ aṣọ àríyá nígbà gbogbo, sì máa fi òróró pa irun rẹ dáradára. Máa gbádùn ayé pẹlu aya rẹ, olólùfẹ́ rẹ, ní gbogbo ọjọ́ asán tí Ọlọrun fún ọ nílé ayé. Nítorí ìpín tìrẹ nìyí láyé ninu làálàá tí ò ń ṣe. Ohunkohun tí o bá ti dáwọ́ lé, fi gbogbo agbára rẹ ṣe é nítorí, kò sí iṣẹ́, tabi èrò, tabi ìmọ̀, tabi ọgbọ́n, ní isà òkú tí ò ń lọ. Bákan náà, mo rí i pé, láyé, ẹni tí ó yára, tí ó lè sáré, lè má borí ninu eré ìje, alágbára lè jagun kó má ṣẹgun, ọlọ́gbọ́n lè má rí oúnjẹ jẹ, eniyan lè gbọ́n kó lóye, ṣugbọn kí ó má lówó lọ́wọ́, ẹni tí ó mọ iṣẹ́ ṣe sì lè má ní ìgbéga, àjálù ati èèṣì lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni. Kò sí ẹni tí ó mọ àkókò tirẹ̀. Bíi kí ẹja kó sinu àwọ̀n burúkú, tabi kí ẹyẹ kó sinu pańpẹ́, ni tàkúté ibi ṣe máa ń mú eniyan, nígbà tí àkókò ibi bá dé bá wọn. Mo tún rí àpẹẹrẹ ọgbọ́n kan nílé ayé, ó sì jẹ́ ohun ribiribi lójú mi. Ìlú kékeré kan wà, tí eniyan kò pọ̀ ninu rẹ̀, ọba ńlá kan wà, ó dótì í, ó sì mọ òkítì sí ara odi rẹ̀. Ọkunrin ọlọ́gbọ́n kan wà níbẹ̀ tí ó jẹ́ talaka, ó gba ìlú náà sílẹ̀ pẹlu ọgbọ́n rẹ̀, ṣugbọn ẹnìkan kò ranti talaka náà mọ́. Sibẹsibẹ, mo rí i pé ọgbọ́n ju agbára lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò ka ọgbọ́n ọkunrin yìí kún, tí kò sì sí ẹni tí ó fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ọ̀rọ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ tí ọlọ́gbọ́n bá sọ, ó dára ju igbe aláṣẹ láàrin àwọn òmùgọ̀ lọ. Ọgbọ́n dára ju ohun ìjà ogun lọ, ṣugbọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kanṣoṣo a máa ba nǹkan ribiribi jẹ́. Bí òkú eṣinṣin ṣe lè ba òórùn turari jẹ́; bẹ́ẹ̀ ni ìwà òmùgọ̀ kékeré lè ba ọgbọ́n ńlá ati iyì jẹ́. Ọkàn ọlọ́gbọ́n eniyan a máa darí rẹ̀ sí ọ̀nà rere, ṣugbọn ọ̀nà burúkú ni ọkàn òmùgọ̀ ń darí rẹ̀ sí. Ìrìn ẹsẹ̀ òmùgọ̀ láàrin ìgboro ń fihàn pé kò gbọ́n, a sì máa fihan gbogbo eniyan bí ó ti gọ̀ tó. Bí aláṣẹ bá ń bínú sí ọ, má ṣe torí rẹ̀ kúrò ní ìdí iṣẹ́ rẹ, ìtẹríba lè mú kí wọn dárí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó bá tóbi jini. Nǹkan burúkú tí mo tún rí láyé ni, irú àṣìṣe tí àwọn aláṣẹ pàápàá ń ṣe: Wọ́n fi àwọn òmùgọ̀ sí ipò gíga, nígbà tí àwọn ọlọ́rọ̀ wà ní ipò tí ó rẹlẹ̀. Mo rí i tí àwọn ẹrú ń gun ẹṣin, nígbà tí àwọn ọmọ-aládé ń fẹsẹ̀ rìn bí ẹrú. Ẹni tí ó gbẹ́ kòtò ni yóo jìn sinu rẹ̀, ẹni tí ó bá já ọgbà wọlé ni ejò yóo bùjẹ. Ẹni tí ó bá ń fọ́ òkúta, ni òkúta í pa lára; ẹni tí ó bá ń la igi, ni igi í ṣe ní jamba. Ẹni tí kò bá pọ́n àáké rẹ̀ kí ó mú, yóo lo agbára pupọ bí ó bá fẹ́ lò ó, ṣugbọn ọgbọ́n a máa ranni lọ́wọ́ láti ṣe àṣeyọrí. Lẹ́yìn tí ejò bá ti buni jẹ tán, kò ṣàǹfààní mọ́ kí á máa pọfọ̀ sí ejò. Ọ̀rọ̀ ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa bu iyì kún un, ṣugbọn ẹnu òmùgọ̀ ni yóo pa á. Agọ̀ ni ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀, wèrè sì ni ìparí rẹ̀. Òmùgọ̀ ń sọ̀rọ̀ láìdákẹ́, kò sí ẹni tí ó mọ ohun tí ń bọ̀ lẹ́yìn ọ̀la, ta ni lè sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀ fún un. Làálàá ọ̀lẹ ń kó àárẹ̀ bá a, tóbẹ́ẹ̀ tí kò mọ ọ̀nà ìlú mọ́. Ilẹ̀ tí ọba rẹ̀ jẹ́ ọmọde gbé! Tí àwọn olórí rẹ̀ ń ṣe àríyá láàárọ̀. Ilẹ̀ tí ọba rẹ̀ kì í bá ṣe ọmọ ẹrú ṣoríire! Tí àwọn olórí rẹ̀ ń ṣe àríyá ní àsìkò tí ó tọ́; tí wọn ń jẹ tí wọn ń mu kí wọn lè lágbára, ṣugbọn tí kì í ṣe fún ìmutípara. Ọ̀lẹ a máa jẹ́ kí ilé ẹni wó, ìmẹ́lẹ́ a máa jẹ́ kí ilé ẹni jò. Oúnjẹ a máa múni rẹ́rìn-ín, waini a sì máa mú inú ẹni dùn, ṣugbọn owó ni ìdáhùn ohun gbogbo. Má bú ọba, kì báà jẹ́ ninu ọkàn rẹ, má sì gbé ọlọ́rọ̀ ṣépè, kì báà jẹ́ ninu yàrá rẹ, nítorí atẹ́gùn lè gbé ọ̀rọ̀ rẹ lọ, tabi kí àwọn ẹyẹ kan lọ ṣòfófó rẹ. Gbin nǹkan ọ̀gbìn káàkiri lọpọlọpọ, o óo sì kórè ọpọlọpọ èso nígbà tó bá yá. Gbin àwọn kan síhìn-ín, gbin àwọn kan sọ́hùn-ún, gbìn ín káàkiri oko nítorí o kò mọ ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la. Nígbà tí òjò bá ṣú dẹ̀dẹ̀, orí ilẹ̀ ni yóo rọ̀ sí, níbi tí igi bá wó sí, níbẹ̀ náà ni yóo wà. Ẹni tí ń wo ojú afẹ́fẹ́ kò ní fún irúgbìn kankan, ẹni tí ó bá sì ń wo ṣúṣú òjò kò ní kórè. Gẹ́gẹ́ bí o kò ti mọ bí ẹ̀mí ṣe ń wọ inú ọmọ ninu aboyún, bẹ́ẹ̀ ni o kò mọ̀ bí Ọlọrun ṣe dá ohun gbogbo. Fún irúgbìn ní àárọ̀, má sì ṣe dáwọ́ dúró ní ìrọ̀lẹ́, nítorí o kò mọ èyí tí yóo dàgbà, bóyá ti òwúrọ̀ ni tabi ti ìrọ̀lẹ́, tabi àwọn mejeeji. Ìmọ́lẹ̀ dára, oòrùn sì dùn-ún wò. Bí eniyan ti wù kí ó pẹ́ láyé tó, kí ó máa yọ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, ṣugbọn kí ó ranti pé ọjọ́ tí òun yóo lò ninu ibojì yóo pọ̀ ju èyí tí òun yóo lò láyé lọ. Asán ni ìgbẹ̀yìn gbogbo ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀. Ìwọ ọdọmọkunrin, máa yọ̀ ní ìgbà èwe rẹ, kí inú rẹ máa dùn; máa ṣe bí ọkàn rẹ ti ń fẹ́, ati bí ó ti tọ́ lójú rẹ. Ṣugbọn ranti pé, Ọlọrun yóo ṣe ìdájọ́ gbogbo ohun tí o bá ṣe. Gbé ìbànújẹ́ kúrò lọ́kàn rẹ, má sì gba ìrora láàyè lára rẹ, nítorí asán ni ìgbà èwe ati ìgbà ọmọde. Ranti ẹlẹ́dàá rẹ ní ìgbà èwe rẹ, kí ọjọ́ ibi tó dé, kí ọjọ́ ogbó rẹ tó súnmọ́ etílé, nígbà tí o óo wí pé, “N kò ní inú dídùn ninu wọn.” Kí oòrùn ati ìmọ́lẹ̀ ati òṣùpá ati ìràwọ̀ tó ṣókùnkùn, kí ìkùukùu tó pada lẹ́yìn òjò; nígbà tí àwọn tí ń ṣọ́ ilé yóo máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, tí ẹ̀yìn àwọn alágbára yóo tẹ̀, tí àwọn òòlọ̀ yóo dákẹ́ jẹ́ẹ́, nítorí pé wọn kò pọ̀ mọ́, tí àwọn tí ń wo ìta láti ojú fèrèsé yóo máa ríran bàìbàì; tí àwọn ìlẹ̀kùn yóo tì ní ìgboro, tí ariwo òòlọ̀ yóo rọlẹ̀, tí ohùn ẹyẹ lásán yóo máa jí eniyan kalẹ̀, tí àwọn ọdọmọbinrin tí wọn ń kọrin yóo dákẹ́; ẹ̀rù ibi gíga yóo máa bani, ìbẹ̀rù yóo sì wà ní ojú ọ̀nà; tí igi alimọndi yóo tanná, tí tata yóo rọra máa wọ́ ẹsẹ̀ lọ, tí ìfẹ́ ọkàn kò ní sí mọ́, nítorí pé ọkunrin ń lọ sí ilé rẹ̀ ayérayé, àwọn eniyan yóo sì máa ṣọ̀fọ̀ kiri láàrin ìgboro; kí ẹ̀wọ̀n fadaka tó já, kí àwo wúrà tó fọ́; kí ìkòkò tó fọ́ níbi orísun omi, kí okùn ìfami tó já létí kànga; kí erùpẹ̀ tó pada sí ilẹ̀ tí ó wà tẹ́lẹ̀, kí ẹ̀mí tó pada tọ Ọlọrun tí ó fúnni lọ. Asán ninu asán, ọ̀jọ̀gbọ́n ní, asán ni gbogbo rẹ̀. Yàtọ̀ sí pé ọ̀jọ̀gbọ́n náà gbọ́n, ó tún kọ́ àwọn eniyan ní ìmọ̀. Ó wádìí àwọn òwe fínnífínní, ó sì tò wọ́n lẹ́sẹẹsẹ. Ó wádìí ọ̀rọ̀ tí ó tuni lára ati ọ̀rọ̀ òdodo, ó sì kọ wọ́n sílẹ̀ pẹlu òtítọ́ ọkàn. Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹ̀gún, bẹ́ẹ̀ ni àkójọ òwe tí olùṣọ́-aguntan kan bá sọ dàbí ìṣó tí a kàn tí ó dúró gbọningbọnin. Ọmọ mi, ṣọ́ra fún ohunkohun tí ó bá kọjá eléyìí, ìwé kíkọ́ kò lópin, àkàjù ìwé a sì máa kó àárẹ̀ bá eniyan. Kókó gbogbo ọ̀rọ̀ náà ni ohun tí a ti gbọ́ tẹ́lẹ̀ pé, bẹ̀rù Ọlọrun, kí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́, nítorí èyí nìkan ni iṣẹ́ ọmọ eniyan. Nítorí Ọlọrun yóo mú gbogbo nǹkan tí eniyan bá ṣe wá sí ìdájọ́, ati gbogbo nǹkan àṣírí, ìbáà ṣe rere tabi burúkú. Àwọn orin tí ó dùn jùlọ tí Solomoni kọ nìwọ̀nyí: Wá fi ẹnu kò mí lẹ́nu, nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ọtí waini lọ. Òróró ìpara rẹ ní òórùn dídùn, orúkọ rẹ dàbí òróró ìkunra tí a tú jáde; nítorí náà ni àwọn ọmọbinrin ṣe fẹ́ràn rẹ. Fà mí mọ́ra, jẹ́ kí á ṣe kíá, ọba ti mú mi wọ yàrá rẹ̀. Inú wa yóo máa dùn, a óo sì máa yọ̀ nítorí rẹ a óo gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí waini lọ; abájọ tí gbogbo àwọn obinrin ṣe fẹ́ràn rẹ! Ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu, mo dúdú lóòótọ́, ṣugbọn mo lẹ́wà, mo dàbí àgọ́ Kedari, mo rí bí aṣọ títa tí ó wà ní ààfin Solomoni. Má wò mí tìka-tẹ̀gbin, nítorí pé mo dúdú, oòrùn tó pa mí ló ṣe àwọ̀ mi bẹ́ẹ̀. Àwọn ọmọ ìyá mi lọkunrin bínú sí mi, wọ́n fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà, ṣugbọn n kò tọ́jú ọgbà àjàrà tèmi alára. Sọ fún mi, ìwọ ẹni tí ọkàn mi fẹ́: níbo ni ò ó máa ń da àwọn ẹran rẹ lọ jẹko? Níbo ni wọ́n ti ń sinmi, nígbà tí oòrùn bá mú? Kí n má baà máa wá ọ kiri, láàrin agbo ẹran àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ? Ìwọ tí o lẹ́wà jùlọ láàrin àwọn obinrin, bí o kò bá mọ ibẹ̀, ṣá máa tẹ̀lé ipa agbo ẹran. Jẹ́ kí àwọn ọmọ ẹran rẹ máa jẹko lẹ́bàá àgọ́ àwọn olùṣọ́-aguntan. Olólùfẹ́ mi, mo fi ọ́ wé akọ ẹṣin tí ń fa kẹ̀kẹ́ ogun Farao. Nǹkan ọ̀ṣọ́ mú kí ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ lẹ́wà, ẹ̀gbà ọrùn sì mú kí ọrùn rẹ lẹ́wà. A óo ṣe àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ wúrà, tí a fi fadaka ṣe ọnà sí lára fún ọ. Nígbà tí ọba rọ̀gbọ̀kú lórí ìjókòó rẹ̀, turari mi ń tú òórùn dídùn jáde. Olùfẹ́ mi dàbí àpò òjíá, bí ó ti sùn lé mi láyà. Olùfẹ́ mi dàbí ìdì òdòdó igi Sipirẹsi, ninu ọgbà àjàrà Engedi. Wò ó! O mà dára o, olólùfẹ́ mi; o lẹ́wà pupọ. Ojú rẹ tutù bíi ti àdàbà. Háà, o mà dára o! Olùfẹ́ mi, o lẹ́wà gan-an ni. Ewéko tútù ni yóo jẹ́ ibùsùn wa. Igi Kedari ni òpó ilé wa, igi firi sì ni ọ̀pá àjà ilé wa. Òdòdó Ṣaroni ni mí, ati òdòdó Lílì tí ó wà ninu àfonífojì. Bí òdòdó lílì ti rí láàrin ẹ̀gún, ni olólùfẹ́ mi rí láàrin àwọn ọmọge. Bí igi ápù ti rí láàrin àwọn igi igbó, ni olùfẹ́ mí rí láàrin àwọn ọmọkunrin. Pẹlu ìdùnnú ńlá ni mo fi jókòó lábẹ́ òjìji rẹ̀, èso rẹ̀ sì dùn lẹ́nu mi. Ó mú mi wá sí ilé àsè ńlá, ìfẹ́ ni ọ̀págun rẹ̀ lórí mi. Fún mi ni èso àjàrà gbígbẹ jẹ, kí ara mi mókun, fún mi ní èso ápù jẹ kí ara tù mí, nítorí pé, àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí. Ó wù mí kí ọwọ́ òsì rẹ̀ wà ní ìgbèrí mi, kí ó sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ fà mí mọ́ra. Mo kìlọ̀ fun yín, ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu, ní orúkọ egbin, ati ti àgbọ̀nrín pé, ẹ kò gbọdọ̀ jí ìfẹ́ títí yóo fi wù ú láti jí. Mo gbọ́ ohùn olùfẹ́ mi, wò ó! Ó ń bọ̀, ó ń fò lórí àwọn òkè ńlá, ó sì ń bẹ́ lórí àwọn òkè kéékèèké. Olólùfẹ́ mi dàbí egbin, tabi ọ̀dọ́ akọ àgbọ̀nrín. Wò ó! Ó dúró lẹ́yìn ògiri ilé wa, ó ń yọjú lójú fèrèsé, ó ń yọjú níbi fèrèsé kékeré tí ó wà lókè. Olùfẹ́ mi bá mi sọ̀rọ̀, ó wí fún mi pé, “Dìde, olùfẹ́ mi, arẹwà mi, jẹ́ kí á máa lọ.” Àkókò òtútù ti lọ, òjò sì ti dáwọ́ dúró. Àwọn òdòdó ti hù jáde, àkókò orin kíkọ ti tó, a sì ti ń gbọ́ ohùn àwọn àdàbà ní ilẹ̀ wa. Àwọn igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ń so èso, àjàrà tí ń tanná, ìtànná wọn sì ń tú òórùn dídùn jáde. Dìde, olùfẹ́ mi, arẹwà mi, jẹ́ kí á máa lọ. Àdàbà mi, tí ó wà ninu pàlàpálá òkúta, ní ibi kọ́lọ́fín òkúta, jẹ́ kí n rójú rẹ, kí n gbọ́ ohùn rẹ, nítorí ohùn rẹ dùn, ojú rẹ sì dára. Mú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ wọ̀n-ọn-nì, àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kéékèèké tí wọn ń ba ọgbà àjàrà jẹ́, nítorí ọgbà àjàrà wa tí ń tanná. Olùfẹ́ mi ni ó ni mí, èmi ni mo sì ni olùfẹ́ mi, ó ń da àwọn ẹran rẹ̀, wọn ń jẹko láàrin òdòdó lílì. Tún pada wá! Olùfẹ́ mi, títí ilẹ̀ yóo fi mọ́, tí òjìji kò ní sí mọ́. Pada wá bí egbin ati akọ àgbọ̀nrín, lórí àwọn òkè págunpàgun. Mo wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́, lórí ibùsùn mi lálẹ́, mo wá a, ṣugbọn n kò rí i; mo pè é, ṣugbọn kò dáhùn. N óo dìde nisinsinyii, n óo sì lọ káàkiri ìlú, n óo wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́, ní gbogbo òpópónà ati ní gbogbo gbàgede. Mo wá a ṣugbọn n kò rí i. Àwọn aṣọ́de rí mi, bí wọ́n ṣe ń lọ káàkiri ìlú. Mo bèèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́?” Mo fẹ́rẹ̀ má tíì kúrò lọ́dọ̀ wọn, ni mo bá rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́. Mo dì í mú, n kò sì jẹ́ kí ó lọ, títí tí mo fi mú un dé ilé ìyá mi, ninu ìyẹ̀wù ẹni tí ó lóyún mi. Mò ń kìlọ̀ fun yín, ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu, mo fi egbin ati àgbọ̀nrín inú igbó búra, pé, ẹ kò gbọdọ̀ jí olùfẹ́ mi, títí yóo fi wù ú láti jí. Kí ló ń jáde bọ̀ láti inú aṣálẹ̀ yìí, tí ó dàbí òpó èéfín, tí ó kún fún òórùn dídùn òjíá ati turari, pẹlu òórùn dídùn àtíkè àwọn oníṣòwò? Wò ó! Solomoni ni wọ́n ń gbé bọ̀, lórí ìtẹ́ rẹ̀, ọgọta akọni ọkunrin, lára àwọn akọni Israẹli, ni ó yí ìtẹ́ rẹ̀ ká. Gbogbo wọn dira ogun pẹlu idà, akọni sì ni wọ́n lójú ogun. Olukuluku dira pẹlu idà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, nítorí ìdágìrì ọ̀gànjọ́. Igi Lẹbanoni ni Solomoni fi ṣe ìtẹ́ rẹ̀. Ó fi fadaka ṣe àwọn ẹsẹ̀ ìjókòó rẹ̀, ó fi wúrà ṣe ẹ̀yìn rẹ̀, Aṣọ elése-àlùkò tí àwọn ọmọbinrin Jerusalẹmu hun ni ó fi ṣe tìmùtìmù ìjókòó rẹ̀. Ẹ jáde lọ, ẹ̀yin ọmọbinrin Sioni, ẹ lọ wo Solomoni ọba, pẹlu adé tí ìyá rẹ̀ fi dé e lórí, ní ọjọ́ igbeyawo, ní ọjọ́ ìdùnnú ati ọjọ́ ayọ̀ rẹ̀. Wò ó! O dára gan-an ni, olólùfẹ́ mi, ẹwà rẹ pọ̀. Ẹyinjú rẹ dàbí ti àdàbà lábẹ́ ìbòjú rẹ, irun orí rẹ dàbí ọ̀wọ́ ewúrẹ́, tí wọn ń sọ̀kalẹ̀ láti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Gileadi. Eyín rẹ dàbí ọ̀wọ́ aguntan tí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ gé irun wọn, tí wọn wá fọ̀; gbogbo wọn gún régé, Kò sí ọ̀kan kan tí ó yọ ninu wọn. Ètè rẹ dàbí òwú pupa; ẹnu rẹ fanimọ́ra, ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ ń dán bí ìlàjì èso Pomegiranate, lábẹ́ ìbòjú rẹ. Ọrùn rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Dafidi, tí a kọ́ fún ihamọra, ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ dàbí ẹgbẹrun (1000) asà tí a kó kọ́, bí apata àwọn akọni jagunjagun tí a kó jọ. Ọmú rẹ mejeeji dàbí ọmọ àgbọ̀nrín meji, tí wọn jẹ́ ìbejì, tí wọn ń jẹko láàrin òdòdó lílì. N óo wà lórí òkè òjíá, ati lórí òkè turari, títí ilẹ̀ yóo fi mọ́, tí òkùnkùn yóo sì lọ. O dára gan-an ni, olùfẹ́ mi! O dára dára, o ò kù síbìkan, kò sí àbààwọ́n kankan lára rẹ. Máa bá mi bọ̀ láti òkè Lẹbanoni, iyawo mi, máa bá mi bọ̀ láti òkè Lẹbanoni. Kúrò ní ṣóńṣó òkè Amana, kúrò lórí òkè Seniri ati òkè Herimoni, kúrò ninu ihò kinniun, ati ibi tí àwọn ẹkùn ń gbé. O ti kó sí mi lẹ́mìí, arabinrin mi, iyawo mi, ẹ̀ẹ̀kan náà tí o ti ṣíjú wò mí, pẹlu nǹkan ọ̀ṣọ́ tí ó wà lọ́rùn rẹ, ni o ti kó sí mi lórí. Ìfẹ́ rẹ ti dùn tó! Arabinrin mi, iyawo mi, ìfẹ́ rẹ dùn ju waini lọ. Òróró ìkunra rẹ dára ju turari-kí-turari lọ. Oyin ní ń kán ní ètè rẹ, iyawo mi, wàrà ati oyin wà lábẹ́ ahọ́n rẹ, òórùn dídùn aṣọ rẹ dàbí òórùn Lẹbanoni. Arabinrin mi dàbí ọgbà tí a ti ti ìlẹ̀kùn rẹ̀. Ọgbà tí a tì ni iyawo mi; àní orísun omi tí a tì ni ọ́. Àwọn ohun ọ̀gbìn inú rẹ tí ń sọ dàbí ọgbà pomegiranate, tí ó kún fún èso tí ó dára jùlọ, àwọn bíi igi hena ati nadi; igi nadi ati Safironi, Kalamusi ati Sinamoni, pẹlu oríṣìíríṣìí igi turari, igi òjíá, ati ti aloe, ati àwọn ojúlówó turari tí òórùn wọn dára jùlọ. Ọgbà tí ó ní orísun omi ni ọ́, kànga omi tútù, àní, odò tí ń ṣàn, láti òkè Lẹbanoni. Dìde, ìwọ afẹ́fẹ́ ìhà àríwá, máa bọ̀, ìwọ afẹ́fẹ́ ìhà gúsù! Fẹ́ sórí ọgbà mi, kí òórùn dídùn rẹ̀ lè tàn káàkiri. Kí olùfẹ́ mi wá sinu ọgbà rẹ̀, kí ó sì jẹ èso tí ó bá dára jùlọ. Mo wọ inú ọgbà mi, arabinrin mi, iyawo mi. Mo kó òjíá ati àwọn turari olóòórùn dídùn mi jọ, mo jẹ afárá oyin mi, pẹlu oyin inú rẹ̀, mo mu waini mi ati wàrà mi. Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ẹ jẹ, kí ẹ sì mu, ẹ mu àmutẹ́rùn, ẹ̀yin olùfẹ́. Mo sùn ṣugbọn ọkàn mi kò sùn. Ẹ gbọ́! Olùfẹ́ mi ń kan ìlẹ̀kùn. Ṣílẹ̀kùn fún mi, arabinrin mi, olùfẹ́ mi, àdàbà mi, olùfẹ́ mi tí ó péye, nítorí pé, ìrì ti mú kí orí mi tutù, gbogbo irun mi ti rẹ, fún ìrì alẹ́. Mo ti bọ́ra sílẹ̀, báwo ni mo ṣe lè tún múra? Mo ti fọ ẹsẹ̀ mi, báwo ni mo ṣe lè tún dọ̀tí rẹ̀? Olùfẹ́ mi gbọ́wọ́ lé ìlẹ̀kùn, ọkàn mi sì kún fún ayọ̀. Mo dìde, mo ṣílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi, gbogbo ọwọ́ mi kún fún òjíá, òróró òjíá sì ń kán ní ìka mi sára kọ́kọ́rọ́ ìlẹ̀kùn. Mo ṣílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi, ṣugbọn ó ti yipada, ó ti lọ. Mo fẹ́rẹ̀ dákú, nígbà tí ó sọ̀rọ̀, mo wá a, ṣugbọn n kò rí i, mo pè é, ṣugbọn kò dáhùn. Àwọn aṣọ́de rí mi bí wọ́n ti ń rìn káàkiri ìlú; wọ́n lù mí, wọ́n ṣe mí léṣe, wọ́n sì gba ìborùn mi. Mo rọ̀ yín, ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu, bí ẹ bá rí olùfẹ́ mi, ẹ bá mi sọ fún un pé: Àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí. Kí ni olùfẹ́ tìrẹ fi dára ju ti àwọn yòókù lọ? Ìwọ arẹwà jùlọ láàrin àwọn obinrin? Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju ti àwọn yòókù lọ? Tí o fi ń kìlọ̀ fún wa bẹ́ẹ̀? Olùfẹ́ mi lẹ́wà pupọ, ó sì pupa, ó yàtọ̀ láàrin ẹgbaarun (10,000) ọkunrin. Orí rẹ̀ dàbí ojúlówó wúrà, irun rẹ̀ lọ́, ó ṣẹ́ léra wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ ó dúdú bíi kóró iṣin. Ojú rẹ̀ dàbí àwọn àdàbà etí odò, tí a fi wàrà wẹ̀, tí wọ́n tò sí bèbè odò. Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ dàbí ebè òdòdó olóòórùn dídùn, tí ń tú òórùn dídùn jáde. Ètè rẹ̀ dàbí òdòdó lílì, tí òróró òjíá ń kán níbẹ̀. Ọwọ́ rẹ̀ dàbí ọ̀pá wúrà, tí a to ohun ọ̀ṣọ́ sí lára. Ara rẹ̀ dàbí eyín erin tí ń dán tí a fi òkúta safire bò. Ẹsẹ̀ rẹ̀ dàbí òpó alabasita tí a gbé ka orí ìtẹ́lẹ̀ wúrà. Ìrísí rẹ̀ dàbí òkè Lẹbanoni, ó rí gbọ̀ngbọ̀nràn bí igi Kedari. Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ dùn, àfi bí oyin, ó wuni lọpọlọpọ. Ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu, òun ni olùfẹ́ mi, òun sì ni ọ̀rẹ́ mi, Níbo ni olùfẹ́ rẹ lọ, ìwọ, arẹwà jùlọ láàrin àwọn obinrin? Níbo ni olùfẹ́ rẹ yà sí, kí á lè bá ọ wá a? Olùfẹ́ mi ti lọ sinu ọgbà rẹ̀, níbi ebè igi turari, ó da ẹran rẹ̀ lọ sinu ọgbà, ó lọ já òdòdó lílì. Olùfẹ́ mi ló ni mí, èmi ni mo sì ni olùfẹ́ mi. Láàrin òdòdó lílì, ni ó ti ń da ẹran rẹ̀. Olùfẹ́ mi, o dára bíi Tirisa. O lẹ́wà bíi Jerusalẹmu, O níyì bíi ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun tí ń gbé ọ̀págun. Yíjú kúrò lọ́dọ̀ mi, nítorí wọn kò jẹ́ kí n gbádùn. Irun orí rẹ dàbí ọ̀wọ́ ewúrẹ́ ninu agbo, tí ń sọ̀kalẹ̀ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Gileadi. Eyín rẹ dàbí ọ̀wọ́ aguntan, tí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ wẹ̀ tán, gbogbo wọn gún régé, kò sì sí ọ̀kan tí ó yọ ninu wọn, Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dàbí ìlàjì èso pomegiranate lábẹ́ ìbòjú rẹ. Àwọn ayaba ìbáà tó ọgọta, kí àwọn obinrin mìíràn sì tó ọgọrin, kí àwọn iranṣẹbinrin sì pọ̀, kí wọn má lóǹkà, sibẹ, ọ̀kan ṣoṣo ni àdàbà mi, olùfẹ́ mi tí ó péye. Ọmọlójú ìyá rẹ̀, ẹni tí kò ní àbààwọ́n lójú ẹni tí ó bí i. Àwọn iranṣẹbinrin ń pe ìyá rẹ̀ ní olóríire. Àwọn ayaba ati àwọn obinrin mìíràn ní ààfin sì ń yìn ín. Ta ni ń yọ bọ̀ bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ yìí, tí ó mọ́ bí ọjọ́, tí ó lẹ́wà bí òṣùpá. Tí ó sì bani lẹ́rù, bí àwọn ọmọ ogun tí wọn dira ogun? Mo lọ sinu ọgbà igi eléso, mo lọ wo ẹ̀ka igi tútù ní àfonífojì, pé bóyá àwọn àjàrà ti rúwé, ati pé bóyá àwọn igi èso pomegiranate tí ń tanná. Kí n tó fura, ìfẹ́ tí ṣe mí bí ẹni tí ó wà ninu ọkọ̀ ogun, tí ara ń wá bíi kí ó bọ́ sójú ogun. Máa pada bọ̀, máa pada bọ̀, ìwọ ọmọbinrin ará Ṣulamu. Máa pada bọ̀, kí á lè máa fi ọ́ ṣe ìran wò. Ẹ óo ṣe máa fi ará Ṣulamu ṣe ìran wò bí ẹni wo ẹni tí ó ń jó níwájú ọ̀wọ́ ọmọ ogun meji? Ẹsẹ̀ rẹ ti dára tó ninu bàtà, ìwọ, ọmọ aládé. Itan rẹ dàbí ohun ọ̀ṣọ́, tí ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà ṣe. Ìdodo rẹ dàbí abọ́, tí kì í gbẹ fún àdàlú waini, ikùn rẹ dàbí òkítì ọkà, tí a fi òdòdó lílì yíká. Ọmú rẹ mejeeji dàbí ọmọ àgbọ̀nrín meji, tí wọn jẹ́ ìbejì. Ọrùn rẹ dàbí ilé-ìṣọ́ tí wọn fi eyín erin kọ́. Ojú rẹ dàbí adágún omi ìlú Heṣiboni, tí ó wà ní ẹnubodè Batirabimu. Imú rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Lẹbanoni, tí ó dojú kọ ìlú Damasku. Orí rẹ dàbí adé lára rẹ, ó rí bí òkè Kamẹli, irun rẹ dàbí aṣọ elése-àlùkò tí ó ṣẹ́ léra, wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ irun orí rẹ ń dá ọba lọ́rùn. O dára, o wuni gan-an, olùfẹ́ mi, ẹlẹgẹ́ obinrin. Ìdúró rẹ dàbí igi ọ̀pẹ, ọyàn rẹ ṣù bí ìdì èso àjàrà. Mo ní n óo gun ọ̀pẹ ọ̀hún, kí n di odi rẹ̀ mú. Kí ọmú rẹ dàbí ìdì èso àjàrà, kí èémí ẹnu rẹ rí bí òórùn èso ápù. Ìfẹnukonu rẹ dàbí ọtí waini tí ó dára jùlọ, tí ń yọ́ lọ lọ́nà ọ̀fun, tí ń yọ́ lọ láàrin ètè ati eyín. Olùfẹ́ mi ló ni mí, èmi ni ọkàn rẹ̀ sì fẹ́. Máa bọ̀, olùfẹ́ mi, jẹ́ kí á jáde lọ sinu pápá, kí á lọ sùn ní ìletò kan. Kí á lọ sinu ọgbà àjàrà láàárọ̀ kutukutu, kí á wò ó bóyá àjàrà ti ń rúwé, bóyá ó ti ń tanná; kí á wò ó bóyá igi Pomegiranate ti ń tanná, níbẹ̀ ni n óo ti fi ìfẹ́ mi fún ọ. Èso Mandirake ń tú òórùn dídùn jáde, ẹnu ọ̀nà wa kún fún oríṣìíríṣìí èso tí ó wuni, tí mo ti pèsè wọn dè ọ́, olùfẹ́ mi, ati tuntun ati èyí tó ti pẹ́ nílé. Ìbá wù mí kí o jẹ́ ọmọ ìyá mi ọkunrin, kí ó jẹ́ pé ọmú kan náà ni a jọ mú dàgbà. Bí mo bá pàdé rẹ níta, tí mo fẹnu kò ọ́ lẹ́nu, kì bá tí sí ẹni tí yóo fi mí ṣe yẹ̀yẹ́. Ǹ bá sìn ọ́ wá sílé ìyá mi, ninu ìyẹ̀wù ẹni tí ó tọ́ mi, ǹ bá fún ọ ní waini dídùn mu, àní omi èso Pomegiranate mi. Ọwọ́ òsì rẹ ìbá wà ní ìgbèrí mi, kí o sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ fà mí mọ́ra! Mo kìlọ̀ fun yín, ẹ̀yin obinrin Jerusalẹmu, pé ẹ kò gbọdọ̀ jí olùfẹ́ mi, títí tí yóo fi wù ú láti jí. Ta ní ń bọ̀ láti inú aṣálẹ̀ yìí, tí ó fara ti olùfẹ́ rẹ̀? Lábẹ́ igi èso ápù ni mo ti jí ọ, níbi tí ìyá rẹ ti rọbí rẹ, níbi tí ẹni tí ó bí ọ ti rọbí. Gbé mi lé oókan àyà rẹ bí èdìdì ìfẹ́, bí èdìdì, ní apá rẹ; nítorí ìfẹ́ lágbára bí ikú. Owú jíjẹ burú, àfi bí isà òkú. A máa jó bí iná, bí ọwọ́ iná tí ó lágbára. Ọ̀pọ̀ omi kò lè pa iná ìfẹ́, ìgbì omi kò sì lè tẹ̀ ẹ́ rì. Bí eniyan bá gbìyànjú láti fi gbogbo nǹkan ìní rẹ̀ ra ìfẹ́, ẹ̀tẹ́ ni yóo fi gbà. A ní àbúrò obinrin kékeré kan, tí kò lọ́mú. Kí ni kí á ṣe fún arabinrin wa náà ní ọjọ́ tí wọ́n bá wá tọrọ rẹ̀? Bí ó bá jẹ pé ògiri ni arabinrin wa, à óo mọ ilé-ìṣọ́ fadaka lé e lórí. Bí ó bá jẹ́ pé ìlẹ̀kùn ni, pákó Kedari ni a óo fi yí i ká. Ògiri ni mí, ọmú mi sì dàbí ilé-ìṣọ́; ní ojú olùfẹ́ mi, mo ní alaafia ati ìtẹ́lọ́rùn. Solomoni ní ọgbà àjàrà kan, ní Baali Hamoni. Ó fi ọgbà náà fún àwọn tí wọn yá a, ó ní kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn mú ẹgbẹrun (1,000) ìwọ̀n owó fadaka wá, fún èso ọgbà rẹ̀. Èmi ni mo ni ọgbà àjàrà tèmi, ìwọ Solomoni lè ní ẹgbẹrun ìwọ̀n owó fadaka, kí àwọn tí wọn yá ọgbà sì ní igba. Ìwọ tí ò ń gbé inú ọgbà, àwọn ẹlẹgbẹ́ mi ń dẹtí, jẹ́ kí n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ. Yára wá, olùfẹ́ mi, yára bí egbin, tabi ọ̀dọ́ akọ àgbọ̀nrín, sí orí àwọn òkè turari olóòórùn dídùn. Ìran tí Aisaya ọmọ Amosi rí sí Juda ati Jerusalẹmu nìyí, nígbà ayé Usaya, Jotamu, Ahasi, ati Hesekaya, àwọn ọba Juda. Máa gbọ́, ìwọ ọ̀run, sì fetí sílẹ̀, ìwọ ayé Nítorí pé OLUWA ń sọ̀rọ̀ Ó ní, “Lẹ́yìn tí mo bọ́ àwọn ọmọ, tí mo tọ́ wọn dàgbà tán, ọ̀tẹ̀ ni wọ́n dì sí mi. Mààlúù mọ olówó rẹ̀; kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sí mọ ibùjẹ tí oluwa rẹ̀ ṣe fún un; ṣugbọn Israẹli kò mọ nǹkan, òye kò yé àwọn eniyan mi.” Háà! Orílẹ̀-èdè tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀, àwọn eniyan tí ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ń pa lọ, ìran oníṣẹ́ ibi; àwọn ọmọ tí ó kún fún ìwà ìbàjẹ́! Wọ́n ti kọ OLUWA sílẹ̀, wọn kò náání Ẹni Mímọ́ Israẹli wọ́n sì ti kẹ̀yìn sí i. Ṣé ẹ fẹ́ kí á tún jẹ yín níyà sí i ni, àbí kí ló dé tí ẹ kò fi jáwọ́ ninu ìwà ọ̀tẹ̀ tí ẹ̀ ń hù? Gbogbo orí yín jẹ́ kìkìdá egbò, gbogbo ọkàn yín sì rẹ̀wẹ̀sì. Láti àtẹ́lẹsẹ̀ dé orí yín, kò síbìkan tí ó gbádùn. Gbogbo ara yín kún fún ọgbẹ́ ati egbò tí ń ṣẹ̀jẹ̀. Ẹnikẹ́ni kò wẹ egbò yín, wọn kò dì wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi òògùn sí wọn. Orílẹ̀-èdè yín ti di ahoro, wọ́n ti dáná sun àwọn ìlú yín. Àwọn àjèjì sì ti jẹ ilẹ̀ yín run níṣojú yín. Ó di ahoro bí èyí tí àwọn àjèjì wó palẹ̀. Ó wá ku Jerusalẹmu bí àtíbàbà ninu ọgbà àjàrà, ati bí ahéré ninu oko ẹ̀gúsí; ó wá dàbí ìlú tí ogun dótì. Bí kò bá ṣe pé OLUWA àwọn ọmọ ogun dá díẹ̀ sí ninu wa ni, à bá rí bí i Sodomu, à bá sì dàbí Gomora. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ̀yin ìjòyè Sodomu: Ẹ fetí sí ẹ̀kọ́ Ọlọrun wa, ẹ̀yin ará Gomora OLUWA ní, “Kí ni gbogbo ẹbọ yín jámọ́ fún mi? Àgbò tí ẹ fi ń rú ẹbọ sísun sí mi ti tó gẹ́ẹ́; bẹ́ẹ̀ náà sì ni ọ̀rá ẹran àbọ́pa. N kò ní inú dídùn sí ẹ̀jẹ̀ mààlúù tabi ti ọ̀dọ́ aguntan tabi ti òbúkọ. Nígbà tí ẹ bá wá jọ́sìn níwájú mi, ta ló bẹ̀ yín ní gbogbo gìrìgìrì lásán, tí ẹ̀ ń dà ninu àgbàlá mi. Ẹ má mú ẹbọ asán wá fún mi mọ́; ohun ìríra ni turari jẹ́ fún mi. Àjọ̀dún ìbẹ̀rẹ̀ oṣù titun, ọjọ́ ìsinmi, ati pípe àpéjọ. Ara mi kò gba ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ̀ ń dàpọ̀ mọ́ ẹ̀sìn mọ́. Ninu ọkàn mi, mo kórìíra àwọn àjọ̀dún oṣù tuntun yín, ati àwọn àjọ̀dún pataki yín. Wọ́n ti di ẹrù wúwo fún mi, n kò lè gbé e mọ́, ó sú mi. “Bí ẹ bá tẹ́wọ́ adura, n óo gbé ojú mi kúrò lọ́dọ̀ yín. Ẹ̀ báà tilẹ̀ gbadura, gbadura n kò ní gbọ́; nítorí ọwọ́ yín kún fún ẹ̀jẹ̀, Ẹ wẹ̀, kí ara yín dá ṣáká. Ẹ má hùwà burúkú níwájú mi mọ́. Ẹ má ṣe iṣẹ́ ibi mọ́. Ẹ lọ kọ́ bí eniyan tí ń ṣe rere. Ẹ máa ṣe ẹ̀tọ́. Ẹ máa ran ẹni tí ara ń ni lọ́wọ́. Ẹ máa gbìjà aláìníbaba, kí ẹ sì máa gba ẹjọ́ opó rò.” OLUWA ní, “Ẹ wá ná, ẹ jẹ́ kí á jọ sọ àsọyé pọ̀. Bí ẹ̀ṣẹ̀ yín tilẹ̀ pọ́n bí iná, yóo di funfun bí ẹfun. Bí ó tilẹ̀ pupa bí aṣọ àlàárì, yóo di funfun bí irun ọmọ aguntan funfun. Bí ẹ bá fẹ́, tí ẹ sì gbọ́ràn, ẹ óo jẹ ire ilẹ̀ náà. Ṣugbọn tí ẹ bá kọ̀, tí ẹ sì ṣoríkunkun; idà ni yóo run yín.” Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA sọ. Ìlú tí ó ti jẹ́ olódodo rí tí ń ṣe bí aṣẹ́wó, ìlú tí ó ti kún fún ẹ̀tọ́ ati òdodo rí, ti kún fún ìpànìyàn. Fadaka rẹ ti di ìdàrọ́ mọ́ ọ lọ́wọ́. Wọ́n ti fi omi lú ọtí waini rẹ. Ọlọ̀tẹ̀ ni àwọn ìjòyè rẹ, ati ẹgbẹ́ olè; gbogbo wọn ni wọ́n fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀, tí wọn sì ń wá ẹ̀bùn káàkiri. Wọn kì í gbèjà aláìníbaba, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í gba ẹjọ́ opó rò. Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Alágbára Israẹli ní: “N óo bínú sí àwọn ọ̀tá mi, n óo sì gbẹ̀san lára àwọn tí ó kórìíra mi. Nígbà tí mo bá gbá ọ mú, n óo finá jó gbogbo àìdára rẹ dànù. N óo sì mú gbogbo ìbàjẹ́ rẹ kúrò. N óo dá àwọn onídàájọ́ rẹ pada sí ipò tí wọn ti wà tẹ́lẹ̀. Ati àwọn olùdámọ̀ràn rẹ, lẹ́yìn náà a óo máa pè ọ́ ní ìlú olódodo.” A óo fi ẹ̀tọ́ ra Sioni pada; a óo sì fi òdodo ra àwọn tí ó bá ronupiwada ninu rẹ pada. Ṣugbọn a óo pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ run, àwọn tí ó kọ OLUWA sílẹ̀ yóo sì ṣègbé. Ojú yóo tì yín, fún àwọn igi Oaku tí ẹ nífẹ̀ẹ́ láti máa bọ. Ojú yóo sì tì yín fún àwọn ọgbà oriṣa tí ẹ yàn. Nítorí pé ẹ óo dàbí igi oaku tí ó wọ́wé, ati bí ọgbà tí kò lómi. Alágbára yóo dàbí ògùṣọ̀, iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ bí ìṣáná. Àwọn mejeeji ni yóo jóná pọ̀, kò sì ní sí ẹni tí yóo lè pa iná náà. Ọ̀rọ̀ tí Aisaya ọmọ Amosi sọ nípa Juda ati Jerusalẹmu nìyí: Ní ọjọ́ iwájú òkè ilé OLUWA yóo fi ìdí múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òkè tí ó ga jùlọ, a óo sì gbé e ga ju àwọn òkè yòókù lọ. Gbogbo orílẹ̀-èdè yóo wá sibẹ. Ọpọlọpọ eniyan ni yóo wá, tí wọn yóo máa wí pé: “Ẹ wá! Ẹ jẹ́ kí á gun òkè OLUWA lọ, kí á lọ sí ilé Ọlọrun Jakọbu, kí ó lè kọ́ wa ní ìlànà rẹ̀, kí á sì lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀. Nítorí pé láti Sioni ni òfin Ọlọrun yóo ti jáde wá ọ̀rọ̀ OLUWA yóo sì wá láti Jerusalẹmu.” Yóo ṣe ìdájọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè; yóo sì bá ọpọlọpọ eniyan wí. Wọn yóo fi idà wọn rọ ọkọ́, wọn yóo sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé. Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́, wọn kò sì ní kọ́ ogun jíjà mọ́. Ẹ̀yin ìdílé Jakọbu ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á rìn ninu ìmọ́lẹ̀ OLUWA. Nítorí o ti ta àwọn eniyan rẹ nù, àní, ìdílé Jakọbu. Nítorí pé àwọn aláfọ̀ṣẹ ará ìhà ìlà oòrùn pọ̀ láàrin wọn, àwọn alásọtẹ́lẹ̀ sì pọ̀ bíi ti àwọn ará Filistini, Wọ́n ti gba àṣà àwọn àjèjì. Wúrà ati fadaka kún ilẹ̀ wọn, ìṣúra wọn kò sì lópin. Ẹṣin kún ilẹ̀ wọn, kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò sì lóǹkà. Ilẹ̀ wọn kún fún oriṣa, wọ́n ń bọ iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn, wọ́n ń wólẹ̀ fún ohun tí wọ́n fọwọ́ ara wọn ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni eniyan ṣe tẹ ara rẹ̀ lórí ba tí ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀. Oluwa, máṣe dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n. Ẹ wọnú àpáta lọ, kí ẹ sì farapamọ́ sinu ilẹ̀. Ẹ sá fún ibinu OLUWA ati ògo ọlá ńlá rẹ̀. A óo rẹ ọlọ́kàn gíga eniyan sílẹ̀, a óo sì rẹ àwọn onigbeeraga sílẹ̀; OLUWA nìkan ni a óo gbéga ní ọjọ́ náà. Nítorí OLUWA àwọn ọmọ ogun ti ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀, tí yóo dojú ìjà kọ àwọn agbéraga, ati àwọn ọlọ́kàn gíga, ati gbogbo nǹkan tí à ń gbéga. Yóo dojú kọ gbogbo igi Kedari ti Lẹbanoni, tí ó ga fíofío, ati gbogbo igi oaku ilẹ̀ Baṣani; ati gbogbo àwọn òkè ńláńlá, ati gbogbo òkè gíga, ati gbogbo ilé-ìṣọ́ gíga ati gbogbo odi tí ó lágbára, ati gbogbo ọkọ̀ ojú omi láti ìlú Taṣiṣi, ati gbogbo ọkọ̀ tí ó dára. Àwọn ọlọ́kàn gíga yóo di ẹni ilẹ̀, a óo sì rẹ àwọn onigbeeraga sílẹ̀. OLUWA nìkan ni a óo gbéga ní ọjọ́ náà, àwọn oriṣa yóo sì pòórá patapata. Àwọn eniyan yóo sá sinu ihò àpáta, wọn yóo sì wọ inú ihò ilẹ̀ lọ, nígbà tí wọ́n bá ń sá fún ibinu OLUWA, ati ògo ọlá ńlá rẹ̀ nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì. Ní ọjọ́ náà, àwọn eniyan óo kó àwọn ère fadaka wọn dànù, ati àwọn ère wúrà tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe, tí wọn tún ń bọ. Wọn yóo dà wọ́n fún àwọn èkúté ati àwọn àdán. Wọn óo wọ inú pàlàpálá àpáta, ati inú ihò àwọn òkè gíga; nígbà tí wọn bá ń sá fún ibinu OLUWA, ati ògo ọlá ńlá rẹ̀, nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì. Ẹ má gbẹ́kẹ̀lé eniyan mọ́. Ẹlẹ́mìí ni òun alára, nítorí pé kí ni ó lè ṣe? Wò ó! OLUWA, OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo mú gbogbo àwọn tí àwọn eniyan gbójúlé kúrò, ati àwọn nǹkan tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ní Jerusalẹmu ati Juda. Yóo gba gbogbo oúnjẹ tí wọ́n gbójúlé, ati gbogbo omi tí wọ́n fi ẹ̀mí tẹ̀. Yóo mú àwọn alágbára ati àwọn ọmọ ogun kúrò, pẹlu àwọn onídàájọ́ ati àwọn wolii, àwọn aláfọ̀ṣẹ ati àwọn àgbààgbà; àwọn olórí aadọta ọmọ ogun, ati àwọn ọlọ́lá, àwọn adáhunṣe ati àwọn pidánpidán, ati àwọn olóògùn. Ọdọmọkunrin ni OLUWA yóo fi jẹ olórí wọn, àwọn ọmọde ni yóo sì máa darí wọn. Àwọn eniyan náà yóo máa fìyà jẹ ara wọn, olukuluku yóo máa fìyà jẹ ẹnìkejì rẹ̀, àwọn aládùúgbò yóo sì máa fìyà jẹ ara wọn. Ọmọde yóo nàró mọ́ àgbàlagbà, àwọn mẹ̀kúnnù yóo máa dìde sí àwọn ọlọ́lá. Nígbà tí ẹnìkan bá dì mọ́ arakunrin rẹ̀, ninu ilẹ̀ baba rẹ̀, tí ó sọ fún un pé, “Ìwọ ní aṣọ ìlékè, nítorí náà, jẹ́ olórí fún wa; gbogbo ahoro yìí yóo sì wà lábẹ́ àkóso rẹ.” Ní ọjọ́ náà, ẹni tí wọn sọ pé kí ó jẹ olórí yóo kígbe pé, “Èmi kò ní jẹ oyè alátùn-únṣe. N kò ní oúnjẹ nílé bẹ́ẹ̀ ni kò sí aṣọ. Ẹ má fi mí ṣe olórí yín.” Nítorí Jerusalẹmu ti kọsẹ̀, Juda sì ti ṣubú. Nítorí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ati ìṣe wọn lòdì sí OLUWA, wọ́n ń tàpá sí ògo wíwà rẹ̀. Ìwà àgàbàgebè wọn ń takò wọ́n; wọ́n ń polongo ẹ̀ṣẹ̀ wọn bíi ti Sodomu: Wọn kò fi bò rárá. Ègbé ni fún wọn, nítorí pé àwọn ni wọ́n mú ibi wá sórí ara wọn. Sọ fún àwọn olódodo pé yóo dára fún wọn nítorí wọn yóo jèrè iṣẹ́ wọn. Ègbé ni fún àwọn eniyan burúkú, kò ní dára fún wọn. Nítorí wọn óo jèrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Ẹ wá wo àwọn eniyan mi! Ọmọde ni àwọn olórí àwọn eniyan mi; àwọn obinrin ní ń pàṣẹ lé wọn lórí. Ẹ̀yin eniyan mi, àwọn olórí yín ń ṣì yín lọ́nà, wọ́n sì ti da ọ̀nà yín rú. OLUWA ti dìde láti ro ẹjọ́ tirẹ̀; ó ti múra tán láti dá àwọn eniyan rẹ̀ lẹ́jọ́ OLUWA yóo pe àwọn àgbààgbà ati àwọn olórí àwọn eniyan rẹ̀ siwaju ìtẹ́ ìdájọ́, yóo sọ fún wọn pé; “Ẹ̀yin ni ẹ jẹ ọgbà àjàrà mi run, ohun tí ẹ jí nílé àwọn talaka ń bẹ nílé yín. Kí ni ẹ rò tí ẹ fi ń tẹ àwọn eniyan mi ní àtẹ̀rẹ́, tí ẹ̀ ń fi ojú àwọn talaka gbolẹ̀?” OLUWA ní, “Nítorí pé àwọn obinrin Jerusalẹmu jẹ́ onigbeeraga, bí wọn bá ń rìn, wọn á gbé ọrùn sókè gangan; wọn á máa ṣẹ́jú bí wọn tí ń yan lọ. Ṣaworo tí ó wà lọ́rùn ẹsẹ̀ wọn a sì máa dún bí wọ́n tí ń gbésẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan. OLUWA yóo mú kí orí àwọn obinrin Jerusalẹmu pá; yóo ṣí aṣọ lórí wọn.” Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo já gbogbo nǹkan ọ̀ṣọ́ wọn dànù; ati ṣaworo ẹsẹ̀ wọn ni, ati ẹ̀gbà orí wọn; ẹ̀gbà ọrùn wọn; ati yẹtí wọn, ẹ̀gbà ọwọ́ wọn ati ìbòrí wọn. Gèlè wọn ati ìlẹ̀kẹ̀ ẹsẹ̀ wọn, ati ìborùn, ìgò ìpara wọn ati òògùn, òrùka ọwọ́ wọn ati òrùka imú, ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ ati ẹ̀wù àwọ̀lékè ati aṣọ wọn, ati àpò ati àwọn aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ funfun, àwọn ìborùn olówó ńlá. Òórùn burúkú yóo wà dípò òórùn dídùn ìpara, okùn yóo wà dípò ọ̀já; orí pípá yóo dípò irun tí wọ́n ṣe lọ́ṣọ̀ọ́, aṣọ ọ̀fọ̀ yóo dípò aṣọ olówó iyebíye. Ìtìjú yóo bò yín dípò ẹwà. Idà ni yóo pa àwọn ọkunrin yín, àwọn akikanju yín yóo kú sógun. Ọ̀fọ̀ ati ẹkún yóo pọ̀ ní ẹnu ibodè Jerusalẹmu. Yóo dàbí obinrin tí wọ́n tú sí ìhòòhò, tí ó jókòó ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀. Tí ó bá di ìgbà náà, obinrin meje yóo rọ̀ mọ́ ọkunrin kan ṣoṣo, wọn óo máa bẹ̀ ẹ́ pé, “A óo máa bọ́ ara wa, a óo sì máa dá aṣọ sí ara wa lọ́rùn. Ṣá máa jẹ́ ọkọ wa, kí á máa jẹ́ orúkọ rẹ; kí o mú ìtìjú kúrò lọ́rọ̀ wa.” Tí ó bá di ìgbà náà, ẹ̀ka igi OLUWA yóo di ohun ẹwà ati iyì. Èso ilẹ̀ náà yóo sì di ohun ògo ati àmúyangàn fún àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n bá kù. Eniyan mímọ́ ni a óo máa pe àwọn tí wọ́n bá kù ní Sioni, àní, àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ní Jerusalẹmu; gbogbo àwọn tí a bá kọ orúkọ wọn sílẹ̀ pé wọ́n wà láàyè ní Jerusalẹmu. Nígbà tí OLUWA bá ti fọ èérí Jerusalẹmu dànù, tí ó sì jó o níná tí ó sì mú ẹ̀bi ìpànìyàn kúrò níbẹ̀, nípa pé kí wọn máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́, ní ọ̀sán, yóo mú kí ìkùukùu bo gbogbo òkè Sioni ati àwọn tí ó ń péjọ níbẹ̀; ní alẹ́, yóo sì fi èéfín ati ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ bò wọ́n. Ògo OLUWA yóo bò wọ́n bí àtíbàbà ati ìbòrí. Yóo dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ oòrùn lọ́sàn-án, yóo jẹ́ ibi ìsásí ati ààbò fún wọn lọ́wọ́ ìjì ati òjò. Ẹ jẹ́ kí n kọrin kan fún olùfẹ́ mi, kí n kọrin nípa ọgbà àjàrà rẹ̀. Olùfẹ́ mi ní ọgbà àjàrà kan ní orí òkè kan tí ilẹ̀ ibẹ̀ lọ́ràá. Ó kọ́ ilẹ̀ rẹ̀, ó sì ṣa gbogbo òkúta ibẹ̀ kúrò. Ó gbin àjàrà dáradára sinu rẹ̀. Ó kọ́ ilé ìṣọ́ gíga sí ààrin rẹ̀, ó sì ṣe ibi tí wọn yóo ti máa fún ọtí sibẹ. Ó ń retí kí àjàrà rẹ̀ so, ṣugbọn èso kíkan ni ó so. Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ati ẹ̀yin ará Juda, mo bẹ̀ yín, ẹ wá ṣe ìdájọ́ láàrin èmi ati ọgbà àjàrà mi. Kí ló tún kù tí ó yẹ kí n ṣe sí ọgbà àjàrà mi tí n kò ṣe? Ìgbà tí mo retí kí ó so èso dídùn, kí ló dé tí ó fi so èso kíkan? Nisinsinyii n óo sọ ohun tí n óo ṣe sí ọgbà àjàrà mi fun yín. N óo tú ọgbà tí mo ṣe yí i ká, iná yóo sì jó o. N óo wó odi tí mo mọ yí i ká, wọn yóo sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀. N óo jẹ́ kí ó di igbó, ẹnikẹ́ni kò ní ro ó mọ́, wọn kò sì ní tọ́jú rẹ̀ mọ́. Ẹ̀gún ati ẹ̀wọ̀n agogo ni yóo hù níbẹ̀. N óo pàṣẹ fún òjò kí ó má rọ̀ sórí rẹ̀ mọ́. Nítorí ilé Israẹli ni ọgbà àjàrà OLUWA ọmọ ogun, àwọn ará Juda ni àjàrà dáradára tí ó gbìn sinu rẹ̀. Ó ń retí kí wọn máa ṣe ẹ̀tọ́, ṣugbọn kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n ń paniyan; ó ń retí ìwà òdodo, ṣugbọn kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn tí wọn ń ni lára ni wọ́n ń kígbe. Ègbé ni fún àwọn tí ó ń kọ́lé mọ́lé, tí wọn ń gba ilẹ̀ kún ilẹ̀, títí tí kò fi sí ilẹ̀ mọ́, kí ẹ̀yin nìkan baà lè máa gbé ilẹ̀ náà. OLUWA ọmọ ogun ti búra lójú mi, ó ní, “Láìsí àní-àní, ọpọlọpọ ilé ni yóo di ahoro, ọ̀pọ̀ ilé ńláńlá, ati ilé dáradára yóo sì wà láìsí olùgbé. Apẹ̀rẹ̀ èso àjàrà kan ni a óo rí ká ninu ọgbà àjàrà sarè mẹ́wàá. Kóńgò èso kan ni ẹni tí ó gbin kóńgò marun-un yóo rí ká.” Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n jí ní òwúrọ̀ kutukutu, láti máa wá ọtí líle kiri, tí wọ́n ń mu ún títí di ìrọ̀lẹ́, títí tí ọtí yóo fi máa pa wọ́n! Dùùrù, hapu, ìlù, fèrè ati ọtí waini wà níbi àsè wọn; ṣugbọn wọn kì í bìkítà fún iṣẹ́ Ọlọrun, wọn kìí sìí náání iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Nítorí náà àwọn eniyan mi óo lọ sí oko ẹrú nítorí àìmòye wọn, ebi ni yóo pa àwọn ọlọ́lá wọn ní àpakú, òùngbẹ óo sì gbẹ ọpọlọpọ wọn. Isà òkú ti ṣetán, yóo gbé wọn mì, ó ti yanu kalẹ̀. Àwọn ọlọ́lá Jerusalẹmu yóo já sinu rẹ́, ati ọ̀pọ̀ ninu àwọn ará ìlú, ati àwọn tí ń fi ìlú Jerusalẹmu yangàn. A tẹ eniyan lórí ba, a sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀ ojú àwọn onigbeeraga yóo sì wálẹ̀. Ṣugbọn OLUWA àwọn ọmọ ogun ni a óo gbéga ninu ẹ̀tọ́ nítorí ìdájọ́ òdodo Ọlọrun Mímọ́ yóo fi ara rẹ̀ hàn, pé mímọ́ ni òun ninu òdodo. Nígbà náà ni àwọn ọ̀dọ́ aguntan yóo máa jẹ oko ninu pápá oko wọn àwọn àgbò ati ewúrẹ́ yóo sì máa jẹko ninu ahoro wọn. Àwọn tí ń ṣe àfọwọ́fà ẹ̀ṣẹ̀ gbé! Àwọn tí wọn ń fi ìwà aiṣododo fa ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹni tí ń fi okùn fa ẹṣin. Tí wọn ń wí pé: “Kí ó tilẹ̀ ṣe kíá, kí ó ṣe ohun tí yóo ṣe, kí á rí i. Jẹ́ kí àbá Ẹni Mímọ́ Israẹli di òtítọ́ kí ó ṣẹlẹ̀, kí á lè mọ̀ ọ́n!” Àwọn tí ń pe ibi ní ire gbé; tí wọn ń pe ire ní ibi! Àwọn tí wọn ń fi òkùnkùn ṣe ìmọ́lẹ̀, tí wọn sì fi ìmọ́lẹ̀ ṣe òkùnkùn! Tí wọ́n fi ìkorò ṣe adùn, tí wọ́n sì fi adùn ṣe ìkorò. Àwọn tí ó gbọ́n lójú ara wọn gbé; tí wọ́n ka ara wọn kún ẹni tí ó ní ìmọ̀! Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọ̀gá ninu ọtí mímu gbé; tí wọ́n jẹ́ akikanju bí ó bá di pé kí á da ọtí líle pọ̀ mọ́ ara wọn! Àwọn tí wọn ń dá ẹni tí ó jẹ̀bi sílẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ti gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tán; tí wọn kì í jẹ́ kí aláìṣẹ̀ rí ẹ̀tọ́ gbà. Nítorí náà, bí iná tíí jó àgékù igi kanlẹ̀, tíí sìí jó ewéko ní àjórun; bẹ́ẹ̀ ní gbòǹgbò wọn yóo ṣe rà, tí ìtànná wọn yóo sì fẹ́ lọ bí eruku. Nítorí wọ́n kọ òfin OLUWA àwọn ọmọ ogun sílẹ̀, wọ́n sì kẹ́gàn ọ̀rọ̀ Ẹni Mímọ́ Israẹli. Nítorí náà ni inú ṣe bí OLUWA sí àwọn eniyan rẹ̀, ó sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì pa wọ́n, àwọn òkè sì mì tìtì. Òkú wọn dàbí pàǹtí láàrin ìgboro, sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì dá ọwọ́ ìjà dúró. Ó ta àsíá, ó fi pe orílẹ̀-èdè kan tí ó wà ní òkèèrè; ó sì fọn fèrè sí i láti òpin ayé. Wò ó! Àwọn eniyan orílẹ̀-èdè náà ń bọ̀ kíákíá. Kò rẹ ẹnikẹ́ni ninu wọn, ẹnikẹ́ni ninu wọn kò fẹsẹ̀ kọ. Ẹyọ ẹnìkan wọn kò sì sùn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tòògbé. Àmùrè ẹnìkankan kò tú, bẹ́ẹ̀ ni okùn bàtà ẹnìkankan kò já. Ọfà wọn mú wọ́n kẹ́ ọrun wọn. Pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin wọn le bí òkúta akọ; ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun wọn dàbí ìjì líle. Bíbú wọn dàbí ti kinniun, wọn a bú ramúramù bí ọmọ kinniun, wọn a kígbe, wọn a sì ki ohun ọdẹ wọn mọ́lẹ̀, wọn a gbé e lọ, láìsí ẹni tí ó lè gbà á lọ́wọ́ wọn. Wọn óo hó lé Israẹli lórí lọ́jọ́ náà bí ìgbà tí omi òkun ń hó. Bí eniyan bá wọ ilẹ̀ náà yóo rí òkùnkùn ati ìnira. Ìkùukùu rẹ̀ yóo sì bo ìmọ́lẹ̀. Ní ọdún tí Usaya Ọba kú, mo rí OLUWA: ó jókòó lórí ìtẹ́, a gbé e ga sókè, aṣọ ìgúnwà rẹ̀ sì kún inú tẹmpili. Àwọn Serafu dúró lókè rẹ̀. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu wọn ní ìyẹ́ mẹfa mẹfa: ó fi meji bo ojú, ó fi meji bo ẹsẹ̀, ó sì ń fi meji fò. Ekinni ń ké sí ekeji pé: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni OLUWA àwọn ọmọ ogun; gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.” Ìpìlẹ̀ ilé náà mì títí nígbà tí ẹni náà kígbe, èéfín sì kún ilé náà. Mo bá pariwo, mo ní, “Mo gbé! Mo ti sọnù, nítorí pé ọ̀rọ̀ ẹnu mi kò mọ́, ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn tí mò ń gbé ààrin wọn náà kò sì mọ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni mo ti fi ojú rí Ọba, OLUWA àwọn ọmọ ogun.” Ọ̀kan ninu àwọn Serafu náà bá fi ẹ̀mú mú ẹ̀yinná kan lórí pẹpẹ, ó mú un lọ́wọ́, ó bá fò wá sọ́dọ̀ mi. Ó sì fi ògúnná náà kàn mí lẹ́nu, ó ní: “Wò ó, èyí ti kàn ọ́ ní ètè: A ti mú ẹ̀bi rẹ kúrò, a sì ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.” Mo wá gbọ́ ohùn OLUWA ó ní, “Ta ni kí n rán? Ta ni yóo lọ fún wa?” Mo bá dáhùn, mo ní: “Èmi nìyí, rán mi.” OLUWA bá ní: “Lọ, sọ fún àwọn eniyan wọnyi pé; wọn óo gbọ́ títí, ṣugbọn kò ní yé wọn; wọn óo wò títí, ṣugbọn wọn kò ní rí nǹkankan. Mú kí ọkàn àwọn eniyan wọnyi ó yigbì, jẹ́ kí etí wọn di. Fi nǹkan bò wọ́n lójú, kí wọn má baà ríran, kí wọn má sì gbọ́ràn, kí òye má baà yé wọn, kí wọn má baà yipada, kí wọn sì rí ìwòsàn.” Mo bá bi í pé: “OLUWA mi, títí di ìgbà wo?” Ó sì dáhùn pé: “Títí tí àwọn ìlú yóo fi di ahoro, láìsí ẹni tí yóo máa gbé inú wọn; títí tí ilé yóo fi tú láì ku ẹnìkan, títí tí ilẹ̀ náà yóo fi di ahoro patapata. Tí OLUWA yóo kó àwọn eniyan lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, tí ibi tí a kọ̀tì yóo sì di pupọ ní ilẹ̀ náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdámẹ́wàá àwọn eniyan náà ni ó kù ní ilẹ̀ náà, sibẹsibẹ iná yóo tún jó o bí igi terebinti tabi igi Oaku, tí kùkùté rẹ̀ wà lórí ilẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gé e lulẹ̀.” Èso mímọ́ ni kùkùté rẹ̀. Nígbà ayé Ahasi, ọmọ Jotamu, ọmọ Usaya, ọba Juda, Resini Ọba Siria ati Peka ọmọ Remalaya, ọba Israẹli wá gbé ogun ti Jerusalẹmu, ṣugbọn wọn kò lè ṣẹgun rẹ̀. Nígbà tí ìròyìn dé ilé ọba Dafidi pé àwọn ará Siria ati Efuraimu ń gbógun bọ̀, ọkàn òun ati àwọn eniyan rẹ̀ mì tìtì bí afẹ́fẹ́ tíí mi igi ninu igbó. OLUWA sọ fún Aisaya pé, “Lọ bá Ahasi, ìwọ ati Ṣeari Jaṣubu, ọmọ rẹ, ní òpin ibi tí wọ́n fa omi dé ní ọ̀nà àwọn alágbàfọ̀. Kí o sọ fún un pé, ṣọ́ra, farabalẹ̀, má sì bẹ̀rù. Má ṣe jẹ́ kí àyà rẹ já rárá nítorí ibinu gbígbóná Resini ati Siria, ati ti ọmọ Remalaya, nítorí wọn kò yàtọ̀ sí àjókù igi iná meji tí ń rú èéfín. Nítorí pé Siria, pẹlu Efuraimu ati ọmọ Remalaya ti pète ati ṣe ọ́ ní ibi. Wọ́n ń sọ pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ gbógun ti Juda, kí á dẹ́rùbà á, ẹ jẹ́ kí á ṣẹgun rẹ̀ kí á sì gbà á, kí á fi ọmọ Tabeeli jọba lórí rẹ̀!’ “Àbá tí wọn ń dá kò ní ṣẹ, ète tí wọn ń pa kò ní rí bẹ́ẹ̀. Ṣebí Damasku ni olú-ìlú Siria, Resini sì ni olórí Damasku. Láàrin ìsinyìí sí ọdún marundinlaadọrin, Efuraimu yóo fọ́nká, kò sì ní jẹ́ orílẹ̀-èdè mọ́. Ṣebí Samaria ni olú-ìlú Efuraimu, Ọmọ Remalaya sì ni olórí Samaria. Bí ẹ kò bá gbàgbọ́ ẹ kò ní fẹsẹ̀ múlẹ̀.” OLUWA tún sọ fún Ahasi pé: “Bèèrè àmì tí ó bá wù ọ́ lọ́wọ́ OLUWA Ọlọrun rẹ–ìbáà jìn bí isà òkú, tabi kí ó ga bí ojú ọ̀run.” Ṣugbọn Ahasi dáhùn, ó ní: “Èmi kò ní bèèrè nǹkankan, n kò ní dán OLUWA wò.” Aisaya bá dáhùn pé, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Dafidi, ṣé eniyan tí ẹ̀ ń yọ lẹ́nu kò to yín, Ọlọrun mi alára lókù tí ẹ tún ń yọ lẹ́nu? Nítorí náà, OLUWA fúnrarẹ̀ yóo fun yín ní àmì kan. Ẹ gbọ́! Ọlọ́mọge kan yóo lóyún yóo sì bí ọmọkunrin kan, yóo pe orúkọ rẹ̀ ní Imanuẹli. Nígbà tí yóo bá fi mọ bí a ti í kọ nǹkan burúkú, tí a sì í yan nǹkan rere, wàrà ati oyin ni àwọn eniyan yóo máa jẹ. Nítorí pé kí ọmọ náà tó mọ bí a ti í kọ nǹkan burúkú tí a sì í yan nǹkan rere, ilẹ̀ àwọn ọba mejeeji tí wọn ń bà ọ́ lẹ́rù yìí yóo ti di ìkọ̀sílẹ̀. “OLUWA yóo mú ọjọ́ burúkú dé bá ìwọ ati àwọn eniyan rẹ ati ilé baba rẹ, ọjọ́ tí kò ì tíì sí irú rẹ̀ rí, láti ìgbà tí Efuraimu ti ya kúrò lára Juda, OLUWA ń mú ọba Asiria bọ̀. “Ní ọjọ́ náà OLUWA yóo súfèé pe àwọn eṣinṣin tí ó wà ní orísun gbogbo odò Ijipti ati àwọn oyin tí ó wà ní ilẹ̀ Asiria. Gbogbo wọn yóo sì rọ́ wá sí ààrin àwọn àfonífojì, ati gbogbo kọ̀rọ̀ kọ̀rọ̀ ní ààrin àpáta, ati ara gbogbo igi ẹlẹ́gùn-ún ati gbogbo pápá. “Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo mú ọba Asiria wá láti òdìkejì odò. Yóo lò ó bí abẹ ìfárí, yóo fi fá irun orí ati irun ẹsẹ̀ dànù, ati gbogbo irùngbọ̀n pàápàá. “Ní ọjọ́ náà, eniyan yóo máa sin ẹyọ mààlúù kékeré kan ati aguntan meji péré, wàrà tí yóo máa rí fún yóo pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé wàrà ati oyin ni yóo máa fi ṣe oúnjẹ jẹ. Nítorí pé wàrà ati oyin ni àwọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà yóo máa jẹ. “Ní ọjọ́ náà, gbogbo ibi tí ẹgbẹrun ìtàkùn àjàrà wà, tí owó rẹ̀ tó ẹgbẹrun ṣekeli fadaka, yóo di igbó ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n agogo ati ẹ̀gún ọ̀gàn. Àwọn eniyan yóo kó ọrun ati ọfà wá sibẹ, nítorí gbogbo ilẹ̀ náà yóo di igbó ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n agogo ati ẹ̀gún ọ̀gàn. Gbogbo ara òkè tí wọn tí ń fi ọkọ́ ro tẹ́lẹ̀, ẹnikẹ́ni kò ní lè débẹ̀ mọ́, nítorí ìbẹ̀rù ẹ̀wọ̀n agogo ati ẹ̀gún ọ̀gàn, gbogbo ibẹ̀ yóo wá di ibi tí mààlúù ati aguntan yóo ti máa jẹko.” Lẹ́yìn náà, OLUWA sọ fún mi pé, “Mú ìwé kan tí ó fẹ̀, kí o kọ Maheriṣalali-haṣi-basi sí i lórí gàdàgbà gàdàgbà.” Mo bá pe Alufaa Uraya ati Sakaraya, ọmọ Jebẹrẹkaya, kí wọn wá ṣe ẹlẹ́rìí mi nítorí wọ́n jẹ́ olóòótọ́. Nígbà tí mo bá iyawo mi, tí òun náà jẹ́ wolii lò pọ̀, ó lóyún, ó sì bí ọmọkunrin. OLUWA bá sọ fún mi pé kí n sọ ọmọ náà ní Maheriṣalali-haṣi-basi. Nítorí kí ọmọ náà tó mọ bí a tí ń pe ‘Baba mi’ tabi ‘Mama mi’, wọn óo ti kó àwọn nǹkan alumọni Damasku ati ìkógun Samaria lọ sí Asiria. OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀ ó ní, “Nítorí pé àwọn eniyan wọnyi kọ omi Ṣiloa tí ń ṣàn wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ sílẹ̀, wọ́n wá ń gbọ̀n jìnnìjìnnì níwájú Resini ati ọmọ Remalaya, nítorí náà, ẹ wò ó, OLUWA yóo gbé ọba Asiria ati gbogbo ògo rẹ̀ dìde wá bá wọn, yóo sì bò wọ́n mọ́lẹ̀ bí omi odò Yufurate, tí ó kún àkúnya, tí ó sì kọjá bèbè rẹ̀. Yóo ya wọ Juda, yóo sì bò ó mọ́lẹ̀ bí ó ti ń ṣàn kọjá lọ, títí yóo fi mù ún dé ọrùn. Yóo ya wọ inú ilẹ̀ rẹ̀ látòkè délẹ̀; yóo sì bo gbogbo rẹ̀ mọ́lẹ̀. Kí Ọlọrun wà pẹlu wa.” Ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, ẹ kó ara yín jọ! A óo fọ yín túútúú. Ẹ fetí sílẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ará ilẹ̀ òkèèrè. Ẹ di ara yín ní àmùrè; a óo fọ yín túútúú. Ẹ di ara yín ní àmùrè, a óo fọ yín túútúú. Bí ẹ gbìmọ̀ pọ̀ ìmọ̀ yín yóo di òfo. Ohun yòówù tí ẹ lè sọ, àpérò yín yóo di asán. Nítorí pé Ọlọrun wà pẹlu wa. Nítorí ọwọ́ agbára ni OLUWA fi lé mi lára, nígbà tí ó ń sọ èyí fún mi. Ó sì ti kìlọ̀ fún mi pé kí n má bá àwọn eniyan wọnyi rìn, ó ní, “Ìwọ kò gbọdọ̀ lọ́wọ́ sí ọ̀tẹ̀ tí àwọn eniyan yìí ń dì. Bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ bẹ̀rù ohun tí wọn ń bẹ̀rù. OLUWA àwọn ọmọ ogun nìkan ni kí o kà sí mímọ́, òun ni kí ẹ̀rù rẹ̀ máa bà ọ́. Òun nìkan ni kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa pá ọ láyà. Yóo di ibi-mímọ́ ati òkúta ìdìgbòlù, ati àpáta tí ó ń mú kí eniyan kọsẹ̀, fún ilẹ̀ Israẹli mejeeji. Yóo di ẹ̀bìtì ati tàkúté fún àwọn ará Jerusalẹmu. Ọ̀pọ̀ eniyan ni yóo kọsẹ̀ níbẹ̀; wọn yóo ṣubú, wọn yóo sì fọ́ wẹ́wẹ́. Tàkúté yóo mú wọn, ọwọ́ yóo sì tẹ̀ wọ́n.” Di ẹ̀rí náà, fi èdìdì di ẹ̀kọ́ náà láàrin àwọn ọmọ ẹ̀yìn mi. N óo dúró de OLUWA ẹni tí ó fojú pamọ́ fún ilé Jakọbu, n óo sì ní ìrètí ninu rẹ̀. Ẹ wò ó! Èmi ati àwọn ọmọ tí OLUWA fún mi, a wà fún àmì ati ìyanu ní Israẹli láti ọ̀dọ̀ OLUWA àwọn ọmọ ogun, tí ń gbé orí òkè Sioni. Nígbà tí wọ́n bá wí fun yín pé kí ẹ lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ àwọn àjẹ́ ati àwọn abókùúsọ̀rọ̀ tí wọn ń jẹ ẹnu wúyẹ́-wúyẹ́. Ṣé kò yẹ kí orílẹ̀-èdè wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọrun wọn? Ṣé lọ́dọ̀ òkú ni ó ti yẹ kí alààyè ti máa wádìí ọ̀rọ̀? Ẹ lọ wádìí ninu ẹ̀kọ́ mímọ́ ati ẹ̀rí. Bí ẹnìkan bá sọ irú ọ̀rọ̀ yìí, kò sí òye ìmọ́lẹ̀ níbẹ̀. Wọn yóo kọjá lọ lórí ilẹ̀ náà ninu ìnira ati ebi; nígbà tí ebi bá pa wọ́n, wọn yóo máa kanra, wọn óo gbé ojú wọn sókè, wọn óo sì gbé ọba ati Ọlọrun wọn ṣépè. Wọn óo bojú wo ilẹ̀, kìkì ìdààmú ati òkùnkùn ati ìṣúdudu ati ìnira ni wọn óo rí. A óo sì sọ wọ́n sinu òkùnkùn biribiri. Ṣugbọn kò ní sí ìṣúdudu fún ẹni tí ó wà ninu ìnira. Ní ìgbà àtijọ́, ó sọ ilẹ̀ Sebuluni ati ilẹ̀ Nafutali di yẹpẹrẹ, ṣugbọn nígbà ìkẹyìn yóo ṣe ilẹ̀ àwọn tí ó ń gbé apá ọ̀nà òkun lógo, títí lọ dé òdìkejì odò Jọdani, ati Galili níbi tí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè mìíràn ń gbé. Àwọn tí ń rìn ninu òkùnkùn ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá. Ìmọ́lẹ̀ sì ti tàn sí àwọn tí ń gbé ninu òkùnkùn biribiri. Ó ti bukun orílẹ̀-èdè náà. Ó ti fi kún ayọ̀ wọn; wọ́n ń yọ̀ níwájú rẹ̀, bí ayọ̀ ìgbà ìkórè. Bí inú àwọn eniyan ti máa ń dùn nígbà tí wọ́n bá ń pín ìkógun. Nítorí pé ó ti ṣẹ́ àjàgà tí ó wọ̀ wọ́n lọ́rùn, ati ọ̀pá tí wọn fí ń ru ẹrù sí èjìká, ati kùmọ̀ àwọn tí ń fìyà jẹ wọ́n. Ó ti ṣẹ́ wọn, bí ìgbà tí ó ṣẹ́ ti àwọn ará Midiani. Gbogbo bàtà àwọn ológun, tí ń kilẹ̀ lójú ogun, ati gbogbo ẹ̀wù tí wọ́n ti yí mọ́lẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ni a óo dáná sun, iná yóo sì jó wọn run. Nítorí a bí ọmọ kan fún wa, a fún wa ní ọmọkunrin kan. Òun ni yóo jọba lórí wa. A óo máa pè é ní Ìyanu, Olùdámọ̀ràn, Ọlọrun alágbára, Baba ayérayé, Ọmọ-Aládé alaafia. Ìjọba rẹ̀ yóo máa tóbi sí i, alaafia kò sì ní lópin ní ìjọba rẹ̀ lórí ìtẹ́ Dafidi. Yóo fìdí rẹ̀ múlẹ̀, yóo sì gbé e ró pẹlu ẹ̀tọ́ ati òdodo, láti ìgbà yìí lọ, títí ayérayé. Ìtara OLUWA àwọn ọmọ ogun ni yóo ṣe èyí OLUWA ranṣẹ ìdájọ́ sí Jakọbu, àní, sórí àwọn ọmọ Israẹli. Gbogbo eniyan ni yóo mọ̀, àwọn ará Efuraimu ati àwọn ará Samaria, àwọn tí wọn ń fọ́nnu pẹlu ìgbéraga pé: Ṣé bíríkì ni wọ́n fi kọ́ àwọn ilé tí ó wó lulẹ̀? Òkúta gbígbẹ́ ni a óo fi tún wọn kọ́. Igi sikamore ni a fi kọ́ èyí tí wọ́n dà wó, ṣugbọn igi kedari dáradára ni a óo lò dípò wọn. Nítorí náà OLUWA ti gbé ọ̀tá dìde sí wọn: Ó ti rú àwọn ọ̀tá wọn sókè sí wọn: Àwọn ará Siria láti ìhà ìlà oòrùn, ati àwọn ará Filistia láti ìhà ìwọ̀ oòrùn; wọn óo gbé Israẹli mì. Sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò dá ọwọ́ ìjà rẹ̀ dúró. Sibẹsibẹ àwọn ọmọ Israẹli kò pada sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó jẹ wọ́n níyà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò wá OLUWA àwọn ọmọ-ogun. Nítorí náà, OLUWA yóo fi ìyà jẹ Israẹli. Ní ọjọ́ kan ṣoṣo, yóo gé Israẹli lórí ati nírù. Àwọn àgbààgbà ati àwọn ọlọ́lá wọn ni orí, àwọn wolii tí ń kọ́ àwọn eniyan ní ẹ̀kọ́ èké sì ni ìrù Àwọn tí ń darí àwọn eniyan wọnyi ń ṣì wọ́n lọ́nà ni, àwọn tí wọn ń tọ́ sọ́nà sì ń já sinu ìparun. Nítorí náà, OLUWA kò láyọ̀ lórí àwọn ọdọmọkunrin wọn, àánú àwọn aláìníbaba ati àwọn opó wọn kò sì ṣe é nítorí pé aṣebi ni gbogbo wọn, wọn kò sì mọ Ọlọrun, ọ̀rọ̀ burúkú ni wọ́n sì ń fi ẹnu wọn sọ. Sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò dá ọwọ́ ìjà rẹ̀ dúró. Ìwà burúkú wọn ń jó bí iná, tí ń jó ẹ̀gún wẹ́wẹ́ ati ẹ̀gún ọ̀gàn. Ó ń jó bíi igbó ńlá, ó sì ń yọ èéfín sókè lálá. Nítorí ibinu OLUWA àwọn ọmọ ogun, ilẹ̀ náà jóná, àwọn eniyan ibẹ̀ dàbí èpò tí a dà sinu iná ẹnikẹ́ni kò sì dá ẹnìkejì rẹ̀ sí. Wọ́n ń já nǹkan gbà lọ́tùn-ún, wọ́n ń jẹ ẹ́, sibẹ ebi ń pa wọ́n. Wọ́n ń jẹ àjẹrun lósì, sibẹ wọn kò yó, àwọn eniyan sì ń pa ara wọn jẹ. Àwọn ará Manase ń bá àwọn ará Efuraimu jà, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Efuraimu náà ń bá àwọn ará Manase jà. Àwọn mejeeji wá dojú ìjà kọ Juda. Sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò dáwọ́ ìjà rẹ̀ dúró. Àwọn tí ń ṣe òfin tí kò tọ́ gbé! Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn akọ̀wé, tí ń kọ̀wé láti ni eniyan lára; wọ́n ń dínà ìdájọ́ òdodo fún àwọn aláìní, wọn kò sì jẹ́ kí àwọn talaka ààrin àwọn eniyan mi rí ẹ̀tọ́ wọn gbà, kí wọ́n lè sọ àwọn opó di ìkógun. Kí ni ẹ óo ṣe lọ́jọ́ ìjìyà yín tí ìparun bá dé láti òkèèrè? Ta ni ẹ óo sá tọ̀ lọ fún ìrànlọ́wọ́? Níbo ni ẹ óo kó ọrọ̀ yín sí? Kò sí ohun tí ó kù àfi kí ẹ kú lójú ogun, tabi kí ẹ ká góńgó láàrin àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú. Sibẹsibẹ inú OLUWA kò ní rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní dá ọwọ́ ìjà rẹ̀ dúró. Háà! Asiria! Orílẹ̀-èdè tí mò ń lò bíi kùmọ̀, ati bíi ọ̀pá nígbà tí inú bá bí mi. Mo rán wọn láti gbógun ti àwọn tí kò mọ Ọlọrun, ati àwọn eniyan tí wọ́n bá mú mi bínú. Pé kí wọ́n kó wọn lẹ́rù. Kí wọ́n kó wọn lẹ́rú kí wọ́n tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bíi ẹrọ̀fọ̀ tí à ń tẹ̀ mọ́lẹ̀ níta gbangba. Ṣugbọn ọba Asiria kò pa irú ète yìí, kò sì ní irú èrò yìí lọ́kàn; gbogbo èrò ọkàn rẹ̀ ni láti pa ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè run nítorí ó wí pé: “Ṣebí ọba ni gbogbo àwọn olórí ogun mi! Ṣebí bíi Kakemiṣi ni Kalino rí, tí Hamati rí bíi Aripadi, tí Samaria kò sì yàtọ̀ sí Damasku? Bí ọwọ́ mi ṣe tẹ àwọn ìlú àwọn abọ̀rìṣà, tí oriṣa wọn lágbára ju ti Jerusalẹmu ati Samaria lọ, ṣé n kò ní lè ṣe sí Jerusalẹmu ati àwọn oriṣa rẹ̀ bí mo ti ṣe Samaria ati àwọn oriṣa rẹ̀?” Nígbà tí OLUWA bá parí bírà tí ó ń dá ní òkè Sioni ati ní Jerusalẹmu, yóo fìyà jẹ ọba Asiria fún ìwà ìgbéraga ati àṣejù rẹ̀. Nítorí ó ní, “Agbára mi ni mo fi ṣe èyí, ọgbọ́n mi ni mo fi ṣe é nítorí pé mo jẹ́ amòye. Mo yí ààlà àwọn orílẹ̀-èdè pada, mo kó ẹrù tí ó wà ninu ilé ìṣúra wọn. Mo ré àwọn tí wọ́n jókòó lórí ìtẹ́ bọ́ sílẹ̀ bí alágbára ọkunrin. Mo nawọ́ kó ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, bí ẹni nawọ́ kó ọmọ ẹyẹ. Mo kó gbogbo ayé, bí ẹni kó ẹyin ẹyẹ tí ó kọ ẹyin rẹ̀ sílẹ̀, tí ó fò lọ, kò sí ẹnìkan tí ó lè ṣe nǹkankan, kò sí ẹnìkan tí ó lanu sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò gbin.” Ǹjẹ́ fáàrí àáké lè pọ̀ ju ti ẹni tí ó ń fi gégi lọ? Tabi ayùn lè fọ́nnu sí ẹni tí ó ń fi rẹ́ igi? Ǹjẹ́ kùmọ̀ lè mú ẹni tí ó ń lò ó lọ́wọ́, tabi kí ọ̀pá mú ẹni tí ó ni í lọ́wọ́? Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo rán àìsàn apanirun sí ààrin àwọn akọni ọmọ ogun rẹ̀. Dípò ohun tí wọ́n fi ń ṣe ògo, ajónirun yóo jó wọn bí ìgbà tí iná bá jóni. Ìmọ́lẹ̀ Israẹli yóo di iná, Ẹni Mímọ́ rẹ̀ yóo di ahọ́n iná; yóo sì jó àwọn ẹ̀gún wẹ́wẹ́ ati ẹ̀gún ọ̀gàn rẹ̀ run ní ọjọ́ kan. OLUWA yóo pa àwọn igi ńlá inú igbó rẹ̀ run, yóo pa àwọn igi eléso ilẹ̀ rẹ́ tèsotèso, bí ìgbà tí àrùn bá gbẹ eniyan. Ohun tí yóo kù ninu àwọn igi igbó rẹ̀ kò ní ju ohun tí ọmọde lè kà, kí ó sì kọ sílẹ̀ lọ. Ní ọjọ́ náà, ìyókù Israẹli ati àwọn tí yóo yè ní agbo ilé Jakọbu, kò ní gbé ara lé ẹni tí ó ṣá wọn lọ́gbẹ́ mọ́, ṣugbọn OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli ni wọn óo fẹ̀yìn tì ní òtítọ́. Àwọn yòókù yóo pada, àwọn yòókù Jakọbu yóo pada sọ́dọ̀ Ọlọrun alágbára. Israẹli, bí àwọn eniyan rẹ tilẹ̀ pọ̀ bí iyanrìn etí òkun, díẹ̀ ninu wọn ni yóo pada, nítorí ìparun ti di òfin ó sì kún fún òdodo Nítorí OLUWA, OLUWA, àwọn ọmọ ogun yóo ṣe iṣẹ́ rẹ̀ ní àṣeparí láàrin gbogbo ayé gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe é lófin. Nítorí náà OLUWA, OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Ẹ̀yin eniyan mi tí ń gbé Sioni, Ẹ má bẹ̀rù àwọn ará Asiria bí wọn bá fi ọ̀gọ lù yín, tabi tí wọn gbé ọ̀pá sókè si yín bí àwọn ará Ijipti ti ṣe si yín. Nítorí pé láìpẹ́, ibinu mi si yín yóo kásẹ̀ nílẹ̀, n óo sì dojú ibinu mi kọ wọ́n láti pa wọ́n run. Èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun, n óo fi ọ̀pá mi nà wọ́n, bí ìgbà tí mo na àwọn ará Midiani ní ibi àpáta Orebu. Ọ̀pá rẹ̀ yóo wà lórí òkun. Yóo tún gbé e sókè bí ó ti ṣe ní Ijipti. Ní ọjọ́ náà, a óo gbé ẹrù tí ó dì lé ọ lórí kúrò, a óo sì fa àjàgà rẹ̀ dá kúrò lọ́rùn rẹ.” Ó ti kúrò ní agbègbè Rimoni, ó ti dé sí Aiati; ó kọjá ní Migironi, ó kó ẹrù ogun rẹ̀ jọ sí Mikimaṣi. Wọ́n sọdá sí òdìkejì odò wọ́n sùn ní Geba di ọjọ́ keji. Àwọn ará Rama ń wárìrì, àwọn ará Gibea, ìlú Saulu sá lọ. Kígbe! Ìwọ ọmọbinrin Galimu. Fetí sílẹ̀ ìwọ Laiṣa, kí Anatoti sì dá a lóhùn. Madimena ń sá lọ, àwọn ará Gebimu ń sá àsálà. Ní òní olónìí, yóo dúró ní Nobu, yóo di ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn òkè Sioni, àní òkè Jerusalẹmu. Ẹ wò ó! OLUWA, OLUWA àwọn ọmọ ogun, yóo gé àwọn ẹ̀ka igi náà pẹlu agbára tí ó bani lẹ́rù. Yóo gé àwọn tí ó ga fíofío lulẹ̀, yóo sì rẹ àwọn agbéraga sílẹ̀. Yóo fi àáké gé àwọn igi igbó tí ó dí, Lẹbanoni pẹlu gbogbo igi ńláńlá rẹ̀ yóo sì wó. Èèhù kan yóo sọ jáde láti inú kùkùté igi Jese, ẹ̀ka kan yóo sì yọ jáde láti inú àwọn gbòǹgbò rẹ̀. Ẹ̀mí OLUWA yóo bà lé e, ẹ̀mí ọgbọ́n ati òye, ẹ̀mí ìmọ̀ràn ati agbára, ẹ̀mí ìmọ̀ ati ìbẹ̀rù OLUWA. Ìbẹ̀rù OLUWA ni yóo jẹ́ ìdùnnú rẹ̀ kì í ṣe ohun tí ó fojú rí, tabi èyí tí ó fi etí gbọ́ ni yóo fi ṣe ìdájọ́. Ṣugbọn yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ àwọn talaka, yóo fi ẹ̀tọ́ gbèjà àwọn onírẹ̀lẹ̀, yóo fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ na ayé bíi pàṣán, yóo sì fi èémí ẹnu rẹ̀ pa àwọn oníṣẹ́ ibi. Òdodo ni yóo fi ṣe àmùrè ìgbàdí rẹ̀, yóo sì fi òtítọ́ ṣe àmùrè ìgbànú rẹ̀. Ìkookò yóo máa bá ọ̀dọ́ aguntan gbé, àmọ̀tẹ́kùn yóo sùn sílẹ̀ pẹlu ọmọ ewúrẹ́, ọmọ mààlúù, ati kinniun, ati ẹgbọ̀rọ̀ ẹran àbọ́pa yóo jọ máa gbé pọ̀, ọmọ kékeré yóo sì máa kó wọn jẹ. Mààlúù ati ẹranko beari yóo jọ máa jẹun pọ̀, àwọn ọmọ wọn yóo jọ máa sùn pọ̀, kinniun yóo sì máa jẹ koríko bí akọ mààlúù. Ọmọ ọmú yóo máa ṣeré lórí ihò paramọ́lẹ̀, ọmọ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ já lẹ́nu ọmú yóo máa fi ọwọ́ bọ inú ihò ejò. Wọn kò ní ṣe eniyan ní jamba mọ́, tabi kí wọ́n bu eniyan jẹ ní gbogbo orí òkè mímọ́ mi. Nítorí ìmọ̀ OLUWA yóo kún gbogbo ayé bí omi ṣe kún gbogbo inú òkun. Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jese yóo dúró bí àsíá fún àwọn orílẹ̀-èdè, òun ni àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa wá. Ibùgbé rẹ̀ yóo jẹ́ èyí tí ó lógo. Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo na ọwọ́ rẹ̀ lẹẹkeji, yóo ra àwọn eniyan rẹ̀ yòókù pada ní oko ẹrú, láti Asiria, ati Ijipti, láti Patosi ati Etiopia, láti Elamu ati Ṣinari, láti Amati ati àwọn erékùṣù òkun. Yóo gbé àsíá sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè, yóo kó àwọn Israẹli tí a ti patì jọ. Yóo ṣa àwọn ọmọ Juda tí wọ́n fọ́nká jọ, láti orígun mẹrẹẹrin ilẹ̀ ayé. Owú jíjẹ Efuraimu yóo kúrò, a óo sì pa àwọn tí ń ni Juda lára run. Efuraimu kò gbọdọ̀ jowú Juda mọ́, bẹ́ẹ̀ ni Juda kò gbọdọ̀ ni Efuraimu lára mọ. Wọn óo kọlu àwọn ará Filistini ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, wọn yóo jọ ṣẹgun àwọn ará ìlà oòrùn. Wọn yóo sì jọ dojú ìjà kọ Edomu ati Moabu. Àwọn ará Amoni yóo gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu. OLUWA yóo pa Ijipti run patapata. Yóo na ọwọ́ ìjì líle sí orí odò Pirati, yóo sì pín in sí ọ̀nà meje, kí àwọn eniyan lè máa ríbi là á kọjá. Ọ̀nà tí ó gbòòrò yóo wà láti Asiria, fún ìyókù àwọn eniyan rẹ̀; bí ó ti ṣe wà fún àwọn ọmọ Israẹli, nígbà tí wọn ń bọ̀ láti Ijipti. O óo sọ ní ọjọ́ náà pé, “N óo fi ọpẹ́ fún OLUWA, nítorí pé bí ó tilẹ̀ bínú sí mi, inú rẹ̀ ti rọ̀, ó sì tù mí ninu. Wò ó! Ọlọrun ni olùgbàlà mi, n óo gbẹ́kẹ̀lé e ẹ̀rù kò sì ní bà mí, nítorí pé OLUWA Ọlọrun ni agbára mi, ati orin mi, òun sì ni Olùgbàlà mi.” Tayọ̀tayọ̀ ni ẹ óo fi máa rí ìgbàlà bí ẹni pọn omi láti inú kànga. Ẹ óo sọ ní ọjọ́ náà pé, “Ẹ fọpẹ́ fún OLUWA, ẹ ké pe orúkọ rẹ̀, ẹ kéde iṣẹ́ rere rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè; ẹ kéde pé a gbé orúkọ rẹ̀ ga. Ẹ kọ orin ìyìn sí OLUWA nítorí ó ṣe nǹkan tí ó lógo, jẹ́ kí èyí di mímọ̀ ní gbogbo ayé. Ẹ̀yin tí ń gbé Sioni, ẹ hó, ẹ kọrin ayọ̀, ẹ̀yin olùgbé Sioni, nítorí Ẹni ńlá ni Ẹni Mímọ́ Israẹli tí ó wà láàrin yín.” Ìran tí Aisaya ọmọ Amosi rí sí Babiloni: Ẹ ta àsíá ní orí òkè gíga, ẹ gbóhùn sókè sí wọn. Ẹ juwọ́, kí àwọn ológun gba ẹnu ibodè àwọn ọlọ́lá wọlé. Èmi pàápàá ti pàṣẹ fún àwọn tí mo yà sọ́tọ̀, mo ti pe àwọn akọni mi, tí mo fi ń yangàn, láti fi ibinu mi hàn. Gbọ́ ariwo lórí òkè, bí ohùn ọ̀pọ̀ eniyan, gbọ́ ariwo ìdàrúdàpọ̀ ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ń péjọ pọ̀! OLUWA àwọn ọmọ ogun ní ń kó àwọn ọmọ ogun jọ fún ogun. Wọ́n wá láti ilẹ̀ òkèèrè, láti ìpẹ̀kun ayé. OLUWA ń bọ̀ pẹlu àwọn ohun ìjà ibinu rẹ̀, tí yóo fi pa gbogbo ayé run. Ẹ pohùnréré ẹkún, nítorí pé ọjọ́ OLUWA súnmọ́lé, yóo dé bí ìparun láti ọwọ́ Olodumare. Nítorí náà ọwọ́ gbogbo eniyan yóo rọ, ọkàn gbogbo eniyan yóo rẹ̀wẹ̀sì; ẹnu yóo sì yà wọ́n. Ìpayà ati ìrora yóo mú wọn, wọn yóo wà ninu ìrora bí obinrin tí ó ń rọbí; wọn óo wo ara wọn tìyanu-tìyanu, ojú yóo sì tì wọ́n. Wò ó! Ọjọ́ OLUWA dé tán, tìkàtìkà pẹlu ìrúnú ati ibinu gbígbóná láti sọ ayé di ahoro, ati láti pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ inú rẹ̀ run. Nítorí àgbájọpọ̀ àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóo kọ̀, wọn kò ní tan ìmọ́lẹ̀. Oòrùn yóo ṣókùnkùn nígbà tí ó bá yọ, òṣùpá kò sì ní tan ìmọ́lẹ̀. N óo fìyà jẹ ayé nítorí iṣẹ́ ibi rẹ̀, n óo sì jẹ àwọn ìkà níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. N óo fòpin sí àṣejù àwọn onigbeeraga, n óo rẹ ìgbéraga àwọn tí kò lójú àánú sílẹ̀. N óo sọ eniyan di ohun tí ó ṣọ̀wọ́n ju wúrà dáradára lọ, irú eniyan yóo ṣọ̀wọ́n ju wúrà ilẹ̀ Ofiri lọ. Nítorí náà n óo mú kí àwọn ọ̀run wárìrì ayé yóo sì mì tìtì tóbẹ́ẹ̀ tí yóo sún kúrò ní ipò rẹ̀, nítorí ibinu OLUWA àwọn ọmọ ogun ní ọjọ́ tí inú rẹ̀ bá ru. Eniyan yóo dàbí àgbọ̀nrín tí ọdẹ ń lé, ati bí aguntan tí kò ní olùṣọ́; olukuluku yóo doríkọ ọ̀dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀, wọn óo sì sá lọ sí ilẹ̀ wọn. Ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá rí, wọn óo fi ọ̀kọ̀ gún un pa, ẹni tí ọwọ́ bá tẹ̀, idà ni wọ́n ó fi pa á. A óo so àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀ lójú wọn, a óo kó ilé wọn, a óo sì bá àwọn obinrin wọn lòpọ̀ pẹlu agbára. Wò ó! N óo rú àwọn ará Media sókè sí wọn, àwọn tí wọn kò bìkítà fún fadaka bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ka wúrà sí. Wọn óo wá bá Babiloni jà. Wọn yóo fi ọfà pa àwọn ọdọmọkunrin, wọn kò ní ṣàánú oyún inú, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ṣàánú àwọn ọmọde. Babiloni, ìwọ tí o lógo jù láàrin gbogbo ìjọba ayé, ìwọ tí o jẹ́ ẹwà ati ògo àwọn ará Kalidea, yóo dàbí Sodomu ati Gomora, nígbà tí Ọlọrun pa wọ́n run. Ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀ láti ìran dé ìran, àwọn ará Arabia kankan kò ní pa àgọ́ sibẹ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn darandaran kankan kò ní jẹ́ kí agbo aguntan wọn sinmi níbẹ̀. Ṣugbọn àwọn ẹranko ní yóo máa sùn níbẹ̀ ilé rẹ̀ yóo sì kún fún ẹyẹ òwìwí, ògòǹgò yóo máa gbè ibẹ̀ ẹhànnà òbúkọ yóo sì máa ta pọ́núnpọ́nún káàkiri ibẹ̀. Àwọn ìkookò yóo máa ké ninu ilé ìṣọ́ rẹ̀, ààfin rẹ̀ yóo di ibùgbé àwọn ajáko, àkókò rẹ̀ súnmọ́ etílé, ọjọ́ rẹ̀ kò sì ní pẹ́ mọ́. OLUWA yóo ṣíjú àánú wo Jakọbu yóo tún yan Israẹli, yóo sì fi wọ́n sórí ilẹ̀ wọn. Àwọn àlejò yóo darapọ̀ mọ́ wọn, wọn yóo sì di ọ̀kan náà pẹlu ilé Jakọbu. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo ràn wọ́n lọ́wọ́ láti pada sí ilẹ̀ wọn, àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi yóo sì di ẹrú fún àwọn ọmọ Israẹli. Wọn yóo pada sọ àwọn tí ó kó wọn lẹ́rú di ẹrú, wọn yóo sì jọba lórí àwọn tí ó ni wọ́n lára. Nígbà tí OLUWA bá fun yín ní ìsinmi kúrò ninu làálàá ati rògbòdìyàn ati iṣẹ́ àṣekára tí wọn ń fi tipá mu yín ṣe, ẹ óo kọrin òwe bú ọba Babiloni pé: “Agbára aninilára ti pin ìpayà ojoojumọ ti dópin. OLUWA ti ṣẹ́ ọ̀pá àṣẹ àwọn ẹni ibi, ati ọ̀pá àṣẹ àwọn olórí tí wọn ń fi ibinu lu àwọn eniyan láì dáwọ́ dúró, tí wọn ń fi ibinu ṣe àkóso àwọn orílẹ̀-èdè, tí ó ń ṣe inúnibíni lemọ́lemọ́. Gbogbo ayé wà ní ìsinmi ati alaafia wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ orin ayọ̀. Àwọn igi Sipirẹsi ń yọ̀ yín; àwọn igi Kedari ti Lẹbanoni sì ń sọ pé, ‘Láti ìgbà tí a ti rẹ ọba Babiloni sílẹ̀, kò sí agégi kan tí ó wá dààmú wa mọ́.’ “Isà òkú ti lanu sílẹ̀ láti pàdé rẹ bí o bá ti ń dé. Ó ta àwọn òkú ọ̀run jí láti kí ọ, àwọn tí wọ́n ṣe pataki ní àkókò wọn, Ó gbé gbogbo àwọn ọba orílẹ̀-èdè dìde lórí ìtẹ́ wọn. Gbogbo wọn yóo wí fún ọ pé, ‘Àárẹ̀ ti mu yín gẹ́gẹ́ bí ó ti mú àwa náà. Ẹ ti dàbí i wa. A ti fa ògo yín ati ohùn hapu yín sinu isà òkú. Ìdin di ibùsùn tí ẹ sùn lé lórí àwọn kòkòrò ni ẹ sì fi bora bí aṣọ.’ “Ọba Babiloni, wò ó! Bí o ti jábọ́ láti ojú ọ̀run, ìwọ tí o dàbí ìràwọ̀ òwúrọ̀! Wò ó bí a ti sọ ọ́ di ẹni ilẹ̀, ìwọ tí o ti pa ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè run rí. Ó pinnu lọ́kàn ara rẹ̀ pé, ‘N óo gòkè dé ọ̀run, n óo gbé ìtẹ́ mi kọjá àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run; n óo jókòó lórí òkè àpéjọ àwọn eniyan, ní ìhà àríwá ní ọ̀nà jíjìn réré. N óo gòkè kọjá ìkùukùu ojú ọ̀run, n óo wá dàbí Olodumare.’ Ṣugbọn a já ọ lulẹ̀ sinu isà òkú, sí ìsàlẹ̀ ọ̀gbun. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá rí ọ yóo tẹjú mọ́ ọ, wọ́n óo fi ọ́ ṣe àríkọ́gbọ́n pé, ‘Ṣé ọkunrin tí ó ń kó ìpayà bá gbogbo ayé nìyí, tí ó ń mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì; ẹni tí ó sọ ayé di aṣálẹ̀, tí ó sì pa àwọn ìlú ńláńlá rẹ̀ run, ẹni tí kì í dá àwọn tí ó bá wà ní ìgbèkùn rẹ̀ sílẹ̀?’ Gbogbo ọba àwọn orílẹ̀-èdè dùbúlẹ̀ ninu ògo wọn olukuluku ninu ibojì tirẹ̀. Ṣugbọn a lé ìwọ kúrò ninu ibojì rẹ, bí ọmọ tí a bí kí oṣù rẹ̀ tó pé, tí a gbé òkú rẹ̀ sọnù; tí a jù sáàrin òkú àwọn jagunjagun tí a pa lójú ogun; àwọn tí a jù sinu kòtò olókùúta, bí àwọn tí a tẹ̀ ní àtẹ̀pa. A kò ní sin ọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọba yòókù, nítorí pé o ti pa ilẹ̀ rẹ run, o sì ti pa àwọn eniyan rẹ. Kí á má dárúkọ àwọn ìran ẹni ibi mọ́ títí lae! Ẹ múra láti pa àwọn ọmọ rẹ̀ run nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wọn, kí wọn má baà tún gbógun dìde, kí wọn gba gbogbo ayé kan, kí wọn sì kọ́ ọpọlọpọ ìlú sórí ilẹ̀ ayé.” OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “N óo gbógun tì wọ́n, n óo pa orúkọ Babiloni rẹ́ ati ìyókù àwọn eniyan tí ó wà ninu rẹ̀, ati arọmọdọmọ wọn. N óo sọ ọ́ di ibùgbé òòrẹ̀, adágún omi yóo wà káàkiri inú rẹ, n óo sì fi ọwọ̀ ìparun gbá a. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA àwọn ọmọ ogun ti búra, ó ní, “Bí mo ti rò ó bẹ́ẹ̀ ni yóo rí; ohun tí mo pinnu ni yóo sì ṣẹ. Pé n óo pa àwọn ará Asiria run lórí ilẹ̀ mi; n óo sì fẹsẹ̀ tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ lórí àwọn òkè mi. Àjàgà rẹ̀ yóo bọ́ kúrò lọ́rùn àwọn eniyan mi, ati ẹrù tí ó dì lé wọn lórí. Ohun tí mo ti pinnu nípa gbogbo ayé nìyí, mo sì ti na ọwọ́ mi sórí orílẹ̀-èdè gbogbo láti jẹ wọ́n níyà.” OLUWA àwọn ọmọ ogun ti pinnu; ta ni ó lè yí ìpinnu rẹ̀ pada? Ó ti dáwọ́lé ohun tí ó fẹ́ ṣe ta ni lè ká a lọ́wọ́ kò? Ọ̀rọ̀ OLUWA tí Aisaya sọ ní ọdún tí ọba Ahasi kú: Gbogbo ẹ̀yin ará Filistini, ẹ má yọ̀ pé a ti ṣẹ́ ọ̀pá tí ó lù yín; nítorí pé paramọ́lẹ̀ ni yóo yọ jáde láti inú àgékù ejò, ejò tí ń fò sì ni ọmọ rẹ̀ yóo yà. Àkọ́bí talaka yóo rí oúnjẹ jẹ, aláìní yóo sì dùbúlẹ̀ láì léwu. Ṣugbọn n óo fi ìyàn pa àwọn ọmọ ilẹ̀ rẹ, a óo sì fi idà pa àwọn tó kù ní ilẹ̀ rẹ. Máa sọkún, ìwọ ẹnubodè, kí ìwọ ìlú sì figbe ta. Ẹ̀yin ará Filistini, ẹ máa gbọ̀n jìnnìjìnnì nítorí pé àwọn ọmọ ogun kan ń rọ́ bọ̀ bí èéfín, láti ìhà àríwá, kò sí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun wọn tí ó ń ṣe dìẹ̀dìẹ̀ bọ̀ lẹ́yìn. Èsì wo ni a óo fún àwọn ikọ̀ orílẹ̀-èdè Filistini? A óo sọ fún wọn pé, “OLUWA ti fi ìdí Sioni sọlẹ̀ àwọn tí à ń pọ́n lójú láàrin àwọn eniyan rẹ̀ yóo fi ibẹ̀ ṣe ibi ààbò.” Ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ nípa ilẹ̀ Moabu nìyí: Nítorí tí a wó ìlú Ari ati Kiri lulẹ̀ ní òru ọjọ́ kan ṣoṣo, ó parí fún Moabu. Àwọn ọmọbinrin Diboni ti gun àwọn ibi pẹpẹ tí wọ́n ti ń bọ̀rìṣà lọ, wọ́n lọ sọkún. Moabu ń pohùnréré ẹkún nítorí Nebo ati Medeba. Gbogbo orí wọn pá, wọ́n sì ti fá gbogbo irùngbọ̀n wọn. Wọ́n da aṣọ ọ̀fọ̀ bora ní ìta gbangba. Gbogbo wọn dúró lórí òrùlé ilé wọn, ati ní gbogbo gbàgede, wọ́n ń pohùnréré ẹkún, omijé sì ń dà lójú wọn. Heṣiboni ati Eleale ń kígbe lóhùn rara, àwọn ará Jahasi gbọ́ ariwo wọn; nítorí náà àwọn ọmọ ogun Moabu sọkún, ọkàn rẹ̀ sì wárìrì. Ọkàn mi sọkún fún Moabu; àwọn ìsáǹsá rẹ̀ sá lọ sí Soari ati Egilati Ṣeliṣiya. Ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Luhiti, wọ́n ń sọkún bí wọ́n ti ń gòkè lọ, wọ́n sì ń kígbe arò bí wọ́n tí ń lọ sí Horonaimu. Àwọn odò Nimrimu di aṣálẹ̀, koríko ibẹ̀ gbẹ; àwọn ohun ọ̀gbìn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yọ jóná mọ́lẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ewé kò rú mọ́. Nítorí náà àwọn ohun tí wọ́n ní lọpọlọpọ ati ohun ìní tí wọn ti kó jọ, ni wọ́n kó lọ sí ìkọjá odò Wilo. Nítorí ariwo kan ti gba gbogbo ilẹ̀ Moabu kan, ẹkún náà dé Egilaimu, ìpohùnréré náà sì dé Beerelimu. Nítorí odò Diboni kún fún ẹ̀jẹ̀, sibẹsibẹ n óo jẹ́ kí ohun tí ó jù bẹ́ẹ̀ lọ dé bá a. Kinniun ni yóo pa àwọn ará Moabu tí ó bá ń sá lọ ati àwọn eniyan tí ó bá kù ní ilẹ̀ náà. Wọ́n ti kó àgbò láti Sela, ní ọ̀nà aṣálẹ̀, wọ́n fi ranṣẹ sí aláṣẹ ilẹ̀ náà, ní òkè Sioni. Àwọn ọmọbinrin Moabu dúró létí odò Anoni, wọ́n ń rìn síwá, sẹ́yìn, wọ́n ń lọ sókè, sódò, bí ọmọ ẹyẹ tí a lé kúrò ninu ìtẹ́. “Gbà wá ní ìmọ̀ràn, máa ṣe ẹ̀tọ́ fún wa. Fi òjìji rẹ dáàbò bò wá, kí ara lè tù wá lọ́sàn-án gangan, bí ẹni pé alẹ́ ni. Dáàbò bo àwọn tí a lé jáde; má tú àṣírí ẹni tí ń sálọ. Jẹ́ kí àwọn tí a lé jáde ní Moabu, máa gbé ààrin yín. Dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn apanirun.” Nígbà tí aninilára kò bá sí mọ́ tí ìparun bá dópin, tí atẹnimọ́lẹ̀ bá ti kúrò ní ilẹ̀ náà. Nígbà náà a óo fìdí ìtẹ́ múlẹ̀ pẹlu ìfẹ́ tí kì í yẹ̀. Ẹnìkan tí ń ṣe ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ati òdodo yóo jókòó lórí ìtẹ́ náà, Yóo dúró lórí òtítọ́ ní ìdílé Dafidi. A ti gbọ́ ìròyìn ìgbéraga Moabu, bí ó ṣe ń ṣe àfojúdi tí ó sì ń sọ ìsọkúsọ: ṣugbọn lásán ni ìgbéraga rẹ̀. Nítorí náà, kí Moabu máa pohùnréré ẹkún, kí gbogbo eniyan máa sun ẹkún arò ní Moabu. Wọn óo sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, nígbà tí wọn ba ranti àkàrà Kiri Heresi, tí ó ní èso àjàrà ninu. Gbogbo oko ni ó rọ ní Heṣiboni; bẹ́ẹ̀ náà ni ọgbà Sibuma: àwọn olórí orílẹ̀-èdè ti gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ lulẹ̀, èyí tí ó tàn kálẹ̀ dé Jaseri títí dé inú aṣálẹ̀. Ìtàkùn rẹ̀ tàn kálẹ̀, wọ́n kọjá sí òdìkejì òkun. Nítorí náà mo sọkún fún ọgbà àjàrà Sibuma bí mo ṣe sọkún fún Jaseri; mo sì sọkún nítorí Heṣiboni ati Eleale, mo sọkún, omi ń dà lójú mi pòròpòrò nítorí gbogbo ìkórè yín, ati èso oko yín ni ogun ti kó lọ. Wọ́n ti kó ayọ̀ ati ìdùnnú lọ kúrò ninu oko eléso; ẹnikẹ́ni kò kọrin bẹ́ẹ̀ ni kò sí ariwo híhó ninu ọgbà àjàrà wọn. Kò sí àwọn tí ó ń pọn ọtí ninu rẹ̀ mọ́ bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọ́ ariwo àwọn tí ń pọn ọtí mọ́. Nítorí náà, ẹ̀mí mi kọrin arò bíi ti dùùrù fún Moabu, ọkàn mi kérora, fún Moabu ati Kiri Heresi. Nígbà tí Moabu bá wá siwaju, tí ó fi gbogbo agbára gbadura ninu ilé oriṣa rẹ̀, títí ó fi rẹ̀ ẹ́, adura rẹ̀ kò ní gbà. Ọ̀rọ̀ tí OLUWA ti kọ́ sọ nípa Moabu tẹ́lẹ̀ nìyí. Ṣugbọn nisinsinyii, OLUWA ní, “Nígbà tí a óo fi rí ọdún mẹta, tíí ṣe iye ọdún alágbàṣe, a óo ti sọ ògo Moabu di ilẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé eniyan inú rẹ̀ pọ̀, àwọn díẹ̀ ni yóo ṣẹ́kù, àárẹ̀ yóo sì ti mú wọn.” Ọ̀rọ̀ OLUWA sí ilẹ̀ Damasku nìyí: “Damasku kò ní jẹ́ ìlú mọ́ òkítì àlàpà ni yóo dà. Àwọn ìlú rẹ̀ yóo di àkọ̀tì títí lae wọn yóo di ibùjẹ àwọn ẹran, níbi tí àwọn ẹran yóo dùbúlẹ̀, tí ẹnikẹ́ni kò sì ní dẹ́rùbà wọ́n. Ìlú olódi kò ní sí mọ́ ní Efuraimu, kò sì ní sí ìjọba mọ́ ní Damasku, àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù ní Siria yóo sì dàbí ògo àwọn ọmọ Israẹli, OLUWA àwọn ọmọ ogun ló sọ bẹ́ẹ̀. “Tó bá di ìgbà náà, a óo rẹ ògo àwọn ọmọ Israẹli sílẹ̀, ọrọ̀ wọn yóo di àìní. Yóo dàbí ìgbà tí eniyan kórè ọkà lóko, tí ó kó ṣiiri ọkà kún apá. Tí àwọn kan tún wá ṣa ọkà yòókù, tí àwọn tí wọn kọ́ kórè ọkà gbàgbé ní àfonífojì Refaimu. Àṣàkù yóo kù níbẹ̀, bí ìgbà tí eniyan gbọn igi olifi, yóo ku meji tabi mẹta péré ní góńgó orí igi, tabi bíi mẹrin tabi marun-un lórí ẹ̀ka igi.” OLUWA Ọlọrun Israẹli ló sọ bẹ́ẹ̀. Tó bá di ìgbà náà, àwọn eniyan yóo bọ̀wọ̀ fún Ẹlẹ́dàá wọn, wọn yóo sì máa wo ojú Ẹni Mímọ́ Israẹli. Wọn kò ní náání pẹpẹ tí wọ́n fọwọ́ ara wọn tẹ́ bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní gbójúlé àwọn ère tí wọ́n fọwọ́ ara wọn ṣe, ìbáà jẹ́ oriṣa Aṣera tabi pẹpẹ turari. Tó bá di ìgbà náà, àwọn ìlú olódi ńláńlá wọn yóo dàbí àwọn ìlú tí àwọn ará Hifi ati àwọn ará Amori sá kúrò níbẹ̀, nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbógun tì wọ́n; gbogbo rẹ̀ yóo di ahoro. Nítorí pé ẹ ti gbàgbé Ọlọrun olùgbàlà yín, ẹ kò ranti Àpáta tí ó jẹ́ ààbò yín. Nítorí náà bí ẹ tilẹ̀ gbin igi dáradára tí ẹ̀ ń bọ ọ́, tí ẹ sì gbin òdòdó àjèjì tí ẹ̀ ń sìn ín; wọn ìbáà hù lọ́jọ́ tí ẹ gbìn wọ́n, kí wọ́n yọ òdòdó ní òwúrọ̀ ọjọ́ tí ẹ lọ́ wọn sibẹsibẹ kò ní sí ìkórè ní ọjọ́ ìbànújẹ́ ati ìrora tí kò lóògùn. Ẹ gbọ́ ariwo ọ̀pọ̀ eniyan, wọ́n ń hó bí ìgbì òkun. Ẹ gbọ́ ìró àwọn orílẹ̀-èdè wọ́n ń hó bíi ríru omi òkun ńlá. Ìró àwọn orílẹ̀-èdè dàbí ti omi òkun ńlá ṣugbọn OLUWA yóo bá wọn wí wọn óo sì sá lọ. Wọn óo dàbí ìràwé tí afẹ́fẹ́ ń gbé lọ lórí òkè, ati bí eruku tí ìjì líle ń fẹ́ kiri. Ìdágìrì yóo bá wọn ní ìrọ̀lẹ́, kí ilẹ̀ tó mọ́ wọn kò ní sí mọ́; bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún àwọn tí wọ́n fogun kó wa, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún àwọn tí wọ́n kó wa lẹ́rù lọ. Ó ṣe, ní òkè àwọn odò kan ní ilẹ̀ Sudani ibìkan wà tí àwọn ẹyẹ ti ń fò pẹ̀ẹ̀rẹ̀pẹ̀. Ẹni tí ó rán ikọ̀ lọ sí òkè odò Naili, tí wọ́n fẹní ṣọkọ̀ ojú omi. Ẹ lọ kíá, ẹ̀yin iranṣẹ ayára-bí-àṣá, ẹ lọ sọ́dọ̀ orílẹ̀-èdè tí ó lágbára, tí ara wọn ń dán, àwọn tí àwọn eniyan tí wọ́n súnmọ́ wọn ati àwọn tí ó jìnnà sí wọn ń bẹ̀rù. Orílẹ̀-èdè tí ó lágbára, tíí sìí máa ń ṣẹgun ọ̀tá, àwọn tí odò la ilẹ̀ wọn kọjá. Gbogbo aráyé, ẹ̀yin tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé, nígbà tí a bá gbé àsíá sókè lórí àwọn òkè, ẹ wò ó, nígbà tí a bá fun fèrè ogun, ẹ gbọ́. Nítorí pé OLUWA sọ fún mi pé òun óo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wolẹ̀ láti ibi ibùgbé òun bí ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán gangan, ati bí ìkùukùu ninu ooru ìgbà ìkórè. Nítorí pé kí ó tó di ìgbà ìkórè, lẹ́yìn tí ìtànná àjàrà bá ti rẹ̀, tí ó di èso, tí àjàrà bẹ̀rẹ̀ sí gbó, tí ó ń pọ́n bọ̀, ọ̀tá yóo ti dòjé bọ àwọn ìtàkùn àjàrà, yóo sì gé gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ kúrò. Gbogbo wọn yóo wà nílẹ̀, wọn yóo di ìjẹ fún àwọn ẹyẹ orí òkè, ati àwọn ẹranko inú ìgbẹ́. Àwọn ẹyẹ yóo fi wọ́n ṣe oúnjẹ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, àwọn ẹranko yóo fi wọ́n ṣe oúnjẹ jẹ ní ìgbà òtútù. Ní àkókò náà, àwọn eniyan tí wọ́n ga, tí wọ́n sì ń dán, tí àwọn tí wọ́n súnmọ́ wọn, ati àwọn tí wọ́n jìnnà sí wọn ń bẹ̀rù, orílẹ̀-èdè tí ó lágbára, tíí sì í máa ń ṣẹgun ọ̀tá, tí odò la ilẹ̀ wọn kọjá, wọn óo mú ẹ̀bùn wá fún OLUWA àwọn ọmọ ogun, ní orí òkè Sioni, tí àwọn eniyan ń jọ́sìn ní orúkọ OLUWA àwọn ọmọ ogun. Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ijipti nìyí: OLUWA gun ìkùukùu lẹ́ṣin, ó ń yára bọ̀ wá sí Ijipti. Àwọn oriṣa Ijipti yóo máa gbọ̀n níwájú rẹ̀, ọkàn àwọn ará Ijipti yóo sì dàrú. N óo dá ìdàrúdàpọ̀ sílẹ̀ láàrin àwọn ará Ijipti, olukuluku yóo máa bá arakunrin rẹ̀ jà, àwọn aládùúgbò yóo máa bá ara wọn jà, ìlú kan yóo gbógun ti ìlú keji, ìjọba yóo máa dìde sí ara wọn. Ìrẹ̀wẹ̀sì yóo dé bá àwọn ará Ijipti, n óo sọ ète wọn di òfo. Wọn yóo lọ máa wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ àwọn oriṣa ati àwọn aláfọ̀ṣẹ ati lọ́dọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀, ati àwọn oṣó. Ṣugbọn n óo fi Ijipti lé aláìláàánú akóniṣiṣẹ́ kan lọ́wọ́ ìkà kan ni yóo sì jọba lé wọn lórí, bẹ́ẹ̀ ni Oluwa, OLUWA àwọn ọmọ ogun wí. Omi odò Naili yóo gbẹ, yóo gbẹ, àgbẹkanlẹ̀. Gbogbo odò wọn yóo máa rùn, gbogbo àwọn odò tí ó ṣàn wọ odò Naili ní Ijipti, ni yóo fà, tí yóo sì gbẹ: Gbogbo koríko odò yóo rà. Etí odò Naili yóo di aṣálẹ̀, gbogbo ohun tí wọ́n bá gbìn sibẹ yóo gbẹ, ẹ̀fúùfù óo sì gbá wọn dànù. Àwọn apẹja tí ń fi ìwọ̀ ninu odò Naili yóo ṣọ̀fọ̀, wọn óo sì sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn; àwọn tí ń fi àwọ̀n pẹja yóo kérora. Ìdààmú yóo bá àwọn tí ó ń hun aṣọ funfun, ati àwọn ahunṣọ tí ń lo òwú funfun. Àwọn eniyan pataki ilẹ̀ náà yóo di ẹni ilẹ̀, ìbànújẹ́ yóo sì bá àwọn alágbàṣe. Òmùgọ̀ ni àwọn olórí wọn ní Soani; ìmọ̀ràn wèrè sì ni àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ìgbìmọ̀ Farao ń fún eniyan. Báwo ni eniyan ṣe lè sọ fún Farao pé, “Ọmọ Ọlọ́gbọ́n eniyan ni mí, ọmọ àwọn ọba àtijọ́.” Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n rẹ dà? Níbo ni wọ́n wà kí wọ́n sọ fún ọ, kí wọ́n sì fi ohun tí OLUWA àwọn ọmọ ogun pinnu láti ṣe sí Ijipti hàn ọ́. Àwọn olórí wọn ní Soani ti di òmùgọ̀, àwọn olórí wọn ní Memfisi sì ti gba ẹ̀tàn; àwọn tí wọ́n jẹ́ òpómúléró ní ilẹ̀ Ijipti ti ṣi Ijipti lọ́nà. OLUWA ti dá èdè-àìyedè sílẹ̀ láàrin wọn, wọ́n sì ti ṣi Ijipti lọ́nà ninu gbogbo ìṣe rẹ̀, bí ìgbà tí ọ̀mùtí bá ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n ninu èébì rẹ̀. Kò sí nǹkankan tí ẹnìkan lè ṣe fún Ijipti, kì báà jẹ́ ọlọ́lá tabi mẹ̀kúnnù, kì báà jẹ́ eniyan pataki tabi ẹni tí kò jẹ́ nǹkan. Tí ó bá di ìgbà náà, àwọn ará Ijipti yóo di obinrin. Wọn yóo máa gbọ̀n, fún ẹ̀rù, nígbà tí OLUWA àwọn ọmọ ogun bá gbá wọn mú. Ilẹ̀ Juda yóo di ẹ̀rù fún àwọn ará Ijipti, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ yóo bẹ̀rù nítorí ohun tí OLUWA àwọn ọmọ ogun ti pinnu láti ṣe sí Ijipti. Tó bá di ìgbà náà, ìlú marun-un yóo wà ní ilẹ̀ Ijipti, tí wọn yóo máa sọ èdè Kenaani; wọ́n óo búra láti jẹ́ ti OLUWA àwọn ọmọ ogun. Orúkọ ọ̀kan ninu wọn yóo máa jẹ́ ìlú Oòrùn. Tó bá di ìgbà náà, wọn yóo tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA láàrin ilẹ̀ Ijipti, ọ̀wọ̀n OLUWA kan yóo sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ààlà ilẹ̀ rẹ̀. Yóo jẹ́ àmì ati ẹ̀rí fún OLUWA àwọn ọmọ ogun ní ilẹ̀ Ijipti. Nígbà tí wọ́n bá ké pe OLUWA nítorí àwọn aninilára, OLUWA yóo rán olùgbàlà tí yóo gbà wọ́n sí wọn. OLUWA yóo sọ ara rẹ̀ di mímọ̀ fún àwọn ará Ijipti, wọn óo sì mọ OLUWA nígbà náà. Wọ́n yóo máa sin OLUWA pẹlu ẹbọ ati ẹbọ sísun; wọn óo jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLUWA, wọn yóo sì mú ẹ̀jẹ́ náà ṣẹ. OLUWA yóo fìyà jẹ àwọn ará Ijipti ṣugbọn yóo wò wọ́n sàn, wọn yóo pada sọ́dọ̀ OLUWA, yóo gbọ́ adura wọn, yóo sì wò wọ́n sàn. Tó bá di ìgbà náà, ọ̀nà tí ó tóbi kan yóo wà láti Ijipti dé Asiria–àwọn ará Asiria yóo máa lọ sí Ijipti, àwọn ará Ijipti yóo sì máa lọ sí Asiria; àwọn ará Ijipti yóo máa jọ́sìn pẹlu àwọn ará Asiria. Ní àkókò náà, Israẹli yóo ṣìkẹta Ijipti ati Asiria, wọn yóo sì jẹ́ ibukun lórí ilẹ̀ fún àwọn ará Ijipti, àwọn eniyan mi. Tí OLUWA àwọn ọmọ ogun ti súre fún pé, “Ibukun ni fún Ijipti, àwọn eniyan mi, ati fún Asiria tí mo fi ọwọ́ mi dá, ati fún Israẹli ìní mi.” Ní ọdún tí Sagoni, ọba Asiria, rán olórí ogun rẹ̀ pé kí ó lọ bá ìlú Aṣidodu jagun, tí ó gbógun ti ìlú náà, tí ó sì gbà á, OLUWA sọ fún Aisaya ọmọ Amosi pé, “Dìde, bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ tí o lọ́ mọ́ra, sì bọ́ bàtà tí o wọ̀ sí ẹsẹ̀.” Aisaya bá ṣe bí OLUWA ti wí: ó bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ lára, ó sì bọ́ bàtà kúrò lẹ́sẹ̀. Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí rìn kiri ní ìhòòhò, láìwọ bàtà. Lẹ́yìn ọdún mẹta, OLUWA dáhùn pé, “Bí Aisaya, iranṣẹ mi, ti rìn ní ìhòòhò tí kò sì wọ bàtà fún ọdún mẹta yìí, jẹ́ àmì ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ilẹ̀ Ijipti ati ilẹ̀ Kuṣi: Bẹ́ẹ̀ ni ọba Asiria yóo ṣe kó àwọn ará Ijipti ati àwọn ará Kuṣi lẹ́rú, ati ọmọde ati àgbàlagbà wọn, ní ìhòòhò, láì wọ bàtà. A óo bọ́ aṣọ kúrò lára wọn, kí ojú ó lè ti Ijipti. Ìbẹ̀rù-bojo yóo dé ba yín, ojú yóo sì tì yín; nítorí Kuṣi ati Ijipti tí ẹ gbójú lé. Àwọn tí ń gbé etí òkun ilẹ̀ yìí yóo wí ní ọjọ́ náà pé, ‘Ẹ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí a gbójú lé, àwọn tí à ń sá tọ̀ lọ pé kí wọ́n ràn wá lọ́wọ́, kí wọ́n gbà wá lọ́wọ́ ọba Asiria. Báwo ní àwa óo ṣe wá là báyìí?’ ” Àsọtẹ́lẹ̀ nípa aṣálẹ̀ etí òkun nìyí: àjálù kan ń já bọ̀ láti inú aṣálẹ̀, láti ilẹ̀ tí ó bani lẹ́rù, ó ń bọ̀ bí ìjì líle tí ń jà bọ̀ láti ìhà àríwá aṣálẹ̀. Ìran tí a fi hàn mí yìí le: Àwọn oníjàgídíjàgan lọ digun kó ìkógun, abanǹkanjẹ́ sì ba nǹkan jẹ́. Ẹ̀yin ará Elamu, ẹ gòkè lọ! Ẹ̀yin ará Media, ẹ múra ogun! Mo ti fòpin sí òṣé ati ìjìyà tí Babiloni kó bá gbogbo eniyan. Nítorí náà, gbogbo ẹ̀gbẹ́ ní ń dùn mí, gbogbo ara ní ń ro mí bí obinrin tí ń rọbí lọ́wọ́. A tẹrí mi ba kí n má baà gbọ́ nǹkankan, wọ́n dẹ́rù bà mí kí n má baà ríran. Ọkàn mi dààmú, jìnnìjìnnì dà bò mí; wọ́n ti sọ àfẹ̀mọ́júmọ́ tí mò ń retí di ìbẹ̀rù mọ́ mi lọ́wọ́. Wọ́n tẹ́ tabili, wọ́n sì tẹ́ aṣọ sílẹ̀ wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu. Ariwo bá ta pé “Ẹ gbéra nílẹ̀, ẹ̀yin ológun! Ẹ fepo pa asà yín.” Nítorí OLUWA wí fún mi pé: “Lọ fi aṣọ́nà ṣọ́ ojú ọ̀nà, kí ó máa kéde ohun tí ó bá rí. Nígbà tí ó bá rí àwọn ẹlẹ́ṣin tí wọn ń bọ̀ ní meji-meji, bí ó bá rí i tí àwọn kan gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, tí àwọn kan gun ràkúnmí, kí ó fara balẹ̀ dáradára, kí ó dẹtísílẹ̀ dáradára.” Ẹni tí ń ṣọ́nà kígbe pé: “OLUWA mi, lórí ilé-ìṣọ́ ni èmi í dúró sí lojoojumọ, níbi tí a fi mí ṣọ́, ni èmi í sì í wà ní òròòru. Ẹ wò ó! Àwọn ẹlẹ́ṣin kan ń bọ̀, wọ́n fẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ ní meji-meji!” “Ẹ gbọ́! Ìlú Babiloni ti wó! Ó ti wó! Pẹlu gbogbo àwọn oriṣa rẹ̀, ó ti wó lulẹ̀ patapata.” Ẹ̀yin eniyan mi tí a ti tẹ̀ mọ́lẹ̀, bí ẹni tẹ ọkà ní ibi ìpakà, ohun tí mo gbọ́ láti ọ̀dọ̀ OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli, ní mò ń kéde fun yín yìí. Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Edomu nìyí: Ẹnìkan ń pè mí láti Seiri Ó ní: “Aṣọ́nà, Òru ti rí o? Aṣọ́nà, àní òru ti rí?” Aṣọ́nà bá dáhùn, ó ní: “Ilẹ̀ ń ṣú, ilẹ̀ sì ń mọ́. Bí ẹ bá tún fẹ́ bèèrè, ẹ pada wá, kí ẹ tún wá bèèrè.” Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Arabia nìyí: Ninu igbó Arabia ni ẹ óo sùn, ẹ̀yin èrò ará Didani. Ẹ bu omi wá fún ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ. Ẹ gbé oúnjẹ pàdé ẹni tí ń sá fógun, ẹ̀yin ará ilẹ̀ Tema. Wọ́n ń sá fún idà, wọ́n sá fún idà lójú ogun. Wọ́n ń sá fún àwọn tafàtafà, wọ́n sá fún líle ogun. OLUWA sọ fún mi pé, “Kí ó tó tó ọdún kan, ní ìwọ̀n ọdún alágbàṣe kan, gbogbo ògo Kedari yóo dópin; díẹ̀ ni yóo sì kù ninu àwọn tafàtafà alágbára ọmọ Kedari; nítorí OLUWA Ọlọrun Israẹli ló sọ bẹ́ẹ̀.” Èyí ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa àfonífojì ìran: Kí ni gbogbo yín ń rò tí ẹ fi gun orí òrùlé lọ, ẹ̀yin tí ìlú yín kún fún ariwo, tí ẹ jẹ́ kìkì ìrúkèrúdò ati àríyá? Gbogbo àwọn tí ó kú ninu yín kò kú ikú idà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kú lójú ogun. Gbogbo àwọn ìjòyè ìlú yín parapọ̀ wọ́n sálọ, láì ta ọfà ni ọ̀tá mú wọn. Gbogbo àwọn tí wọn rí ni wọ́n mú, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti sá jìnnà. Nítorí náà, ni mo ṣe sọ pé, “Ẹ ṣíjú kúrò lára mi ẹ jẹ́ kí n sọkún, kí n dami lójú pòròpòrò, ẹ má ṣòpò pé ẹ óo rẹ̀ mí lẹ́kún, nítorí ìparun àwọn ará Jerusalẹmu, àwọn eniyan mi.” Nítorí OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ti ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀, ọjọ́ ìrúkèrúdò ati ìdágìrì ati ìdàrúdàpọ̀, ní àfonífojì ìran. Ọjọ́ wíwó odi ìlú palẹ̀ ati igbe kíké láàrin àwọn òkè ńlá. Àwọn ọmọ ogun Elamu gbé ọfà wọn kọ́ èjìká, pẹlu kẹ̀kẹ́-ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin, àwọn ọmọ ogun Kiri sì tọ́jú asà wọn. Àwọn àfonífojì dáradára yín kún fún kẹ̀kẹ́-ogun àwọn ẹlẹ́ṣin sì dúró sí ipò wọn lẹ́nu ibodè; ó ti tú aṣọ lára Juda. Ní ọjọ́ náà, ẹ gbẹ́kẹ̀lé àwọn ohun ìjà tí ó wà ninu Ilé-Igbó, ẹ rí i pé ibi tí ògiri ìlú Dafidi ti sán pọ̀, ẹ sì gbá omi inú adágún tí ó wà ní ìsàlẹ̀ jọ. Ẹ ka iye ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu, ẹ sì wó àwọn kan palẹ̀ ninu wọn, kí ẹ lè rí òkúta tún odi ìlú ṣe. Ẹ wa kòtò sí ààrin ògiri mejeeji, Kí ẹ lè rí ààyè fa omi inú odò àtijọ́ sí. Ṣugbọn ẹ kò wo ojú ẹni tí ó ṣe ohun tí ń ṣẹlẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò bìkítà fún ẹni tí ó ṣètò rẹ̀ láti ìgbà pípẹ́ wá. Ní ọjọ́ náà, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun fi ìpè sóde pé, kí ẹ máa sọkún, kí ẹ máa ṣọ̀fọ̀, kí ẹ fá orí yín, kí ẹ sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora. Ṣugbọn dípò kí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀ ń yọ̀, inú yín ń dùn. Ẹ̀ ń pa mààlúù, ẹ̀ ń pa aguntan, ẹ̀ ń jẹ ẹran, ẹ̀ ń mu ọtí waini. Ẹ̀ ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á jẹ, kí á mu! Nítorí pé lọ́la ni a óo kú.” OLUWA àwọn ọmọ ogun ti fi tó mi létí pé: “A kò ní dárí ẹ̀ṣẹ̀ yìí jì yín títí tí ẹ óo fi kú.” OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní, “Lọ bá Ṣebina, iranṣẹ ọba, tí ó jẹ́ olórí ní ààfin ọba, Kí o bi í pé: ‘Kí ni o fẹ́ máa ṣe níhìn-ín? Ta ni o sì ní níhìn-ín tí o fi gbẹ́ ibojì síhìn-ín fún ara rẹ? Ìwọ tí o gbẹ́ ibojì sórí òkè, tí o kọ́ ilé fún ara rẹ ninu àpáta? Wò ó! OLUWA yóo fi tipátipá wọ́ ọ sọnù ìwọ alágbára. Yóo gbá ọ mú tipátipá. Yóo fì ọ́ nàkànnàkàn, yóo sì sọ ọ́ nù bíi bọ́ọ̀lù, sí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú, níbẹ̀ ni óo kú sí. Níbẹ̀ ni àwọn kẹ̀kẹ́-ogun rẹ tí ó dára yóo wà, ìwọ tí ò ń kó ìtìjú bá ilé OLUWA rẹ. N óo tì ọ́ kúrò ní ààyè rẹ, n óo fà ọ́ lulẹ̀ kúrò ní ipò rẹ.’ “Ní ọjọ́ náà, n óo pe Eliakimu, iranṣẹ mi, ọmọ Hilikaya. N óo gbé aṣọ rẹ wọ̀ ọ́, n óo sì dì í ní àmùrè rẹ; n óo gbé àṣẹ rẹ lé e lọ́wọ́, yóo sì di baba fún àwọn ará Jerusalẹmu ati àwọn ará ilé Juda. N óo fi í ṣe alákòóso ilé Dafidi. Ìlẹ̀kùn tí ó bá ṣí, kò ní sí ẹni tí yóo lè tì í; èyí tí ó bá tì, kò ní sí ẹni tí yóo lè ṣí i. N óo fìdí rẹ̀ múlẹ̀ bí èèkàn tí a kàn mọ́ ilẹ̀ tí ó le, yóo di ìtẹ́ iyì fún ilé baba rẹ̀. “Gbogbo ẹbí rẹ̀ ní agboolé baba rẹ̀ yóo di ẹrú rẹ̀, ati àwọn ọmọ ati àwọn ohun èlò, láti orí ife ìmumi, títí kan ìgò ọtí.” OLUWA àwọn ọmọ-ogun ní, “Ní ọjọ́ náà, èèkàn tí a kàn mọ́lẹ̀ gbọningbọnin yóo yọ, wọn yóo gé e, yóo sì wó lulẹ̀, ẹrù tí wọn fi kọ́ lórí rẹ̀ yóo sì já dànù.” Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA sọ. Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Tire nìyí: Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin ọlọ́kọ̀ ojú omi ìlú Taṣiṣi; nítorí pé Tire ti di ahoro, láìsí ilé tabi èbúté! Ní ilẹ̀ Kipru ni a ti fi eléyìí hàn wọ́n. Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́, ẹ̀yin tí ń gbé etí òkun, ẹ̀yin oníṣòwò ará Sidoni; àwọn iranṣẹ yín ti kọjá sí òdìkejì òkun, wọ́n gba orí alagbalúgbú omi kọjá lọ. Èrè yín ni ọkà ìlú Sihori, ìkórè etí odò Naili. Ẹ̀yin ni ẹ̀ ń ṣòwò káàkiri àgbáyé. Ojú tì ọ́, ìwọ Sidoni nítorí òkun ti fọhùn, agbami òkun ti sọ̀rọ̀, ó ní: “N kò rọbí, bẹ́ẹ̀ ni n kò bímọ; n kò tọ́ àwọn ọmọ dàgbà rí kì báà ṣe ọmọkunrin tabi ọmọbinrin.” Nígbà tí ìròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Tire bá dé Ijipti àwọn ará Ijipti yóo kérora. Ẹ kọjá lọ sí Taṣiṣi. Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin tí ó ń gbé etí òkun. Ṣé ìlú olókìkí yín náà nìyí, tí a ti tẹ̀dó láti ìgbà àtijọ́! Tí ó fi ẹsẹ̀ rẹ̀ rìn lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, tí ó ṣe àlejò lọ sibẹ! Ta ni ó gbìmọ̀ irú èyí sí Tire, Ìlú tí ń fún àwọn ọba ìlú yòókù ládé? Tí ó jẹ́ pé kìkì ìjòyè ni àwọn oníṣòwò rẹ̀; gbogbo àwọn tí ń ta ọjà níbẹ̀ ni wọ́n jẹ́ ọlọ́lá ní gbogbo ayé. OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó pinnu láti ba gbogbo iyì ògo jẹ, ati láti tẹ́ gbogbo àwọn ọlọ́lá ayé. Ẹ̀yin ará Taṣiṣi, ẹ máa tàn ká orí ilẹ̀ yín títí ẹ ó fi kan odò Naili, kò sí èbúté tí yóo da yín dúró mọ́. OLUWA ti na ọwọ́ rẹ̀ sórí òkun Ó ti mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì. Ó ti pàṣẹ nípa ilẹ̀ Kenaani pé kí wọ́n pa gbogbo ibi ààbò rẹ̀ run. Ó ní, “Àríyá yín ti dópin, ẹ̀yin ọmọ Sidoni tí à ń ni lára. Ò báà dìde kí o lọ sí Kipru, ara kò ní rọ̀ ọ́ níbẹ̀.” Ẹ wo ilẹ̀ àwọn ará Kalidea! Bí wọ́n ṣe wà bí aláìsí. Àwọn Asiria ti pinnu láti sọ Tire di ibùgbé àwọn ẹranko, wọ́n gbé àkàbà ogun ti odi rẹ̀. Wọ́n fogun kó àwọn ilé ìṣọ́ rẹ̀, wọ́n sì sọ ọ́ di ahoro. Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin ọkọ̀ ojú omi Taṣiṣi, nítorí àwọn ilé ìṣọ́ yín tí ó lágbára ti wó. Nígbà, tó bá yá, Tire yóo di ìgbàgbé fún aadọrin ọdún gẹ́gẹ́ bí iye ọjọ́ ọba kan; lẹ́yìn aadọrin ọdún ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí Tire yóo dàbí orin kan tí àwọn aṣẹ́wó máa ń kọ pé: “Mú hapu, kí o máa káàkiri ààrin ìlú, ìwọ aṣẹ́wó, ẹni ìgbàgbé. Máa kọ orin dídùn ní oríṣìíríṣìí, kí á lè ranti rẹ.” Nígbà tí aadọrin ọdún bá pé, OLUWA yóo ranti Tire. Yóo pada sídìí òwò aṣẹ́wó rẹ̀, yóo sì máa bá gbogbo ìjọba tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé ṣe òwò àgbèrè. Yóo ya ọjà tí ó ń tà ati èrè tí ó bá jẹ sọ́tọ̀ fún OLUWA, kò ní máa to èrè rẹ̀ jọ, tabi kí ó máa kó o pamọ́; ṣugbọn yóo máa lò wọ́n láti pèsè oúnjẹ ati aṣọ fún àwọn tí ó bá ń sin OLUWA. Ẹ wò ó! OLUWA yóo fọ́ gbogbo ayé wómúwómú yóo sì sọ ọ́ di ahoro. Yóo dojú rẹ̀ rú, yóo sì fọ́n àwọn eniyan inú rẹ̀ ká. Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ará ìlú ni yóo ṣẹlẹ̀ sí alufaa; ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ẹrú yóo ṣẹlẹ̀ sí olówó rẹ̀; ohun tí ó ṣe ọmọ-ọ̀dọ̀ ni yóo ṣe ọ̀gá rẹ̀; ohun tí ó ṣe ẹni tí ń rà ni yóo ṣe ẹni tí ń tà. Ohun tí ó ṣe ẹni tí ń yá ni lówó ni yóo ṣe ẹni tí à ń yá lówó. Ohun tí ó ṣe onígbèsè ni yóo ṣe ẹni tí a jẹ lówó. Ogun yóo kó ilé ayé, yóo di òfo patapata. Nítorí OLUWA ni ó sọ bẹ́ẹ̀. Ilẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀, gbogbo nǹkan ń rọ. Ayé ń joró, ó sì ń ṣá àwọn ọ̀run ń joró pẹlu. Àwọn tí ń gbé inú ayé ti ba ilé ayé jẹ́, nítorí pé wọ́n ti rú àwọn òfin wọ́n ti tàpá sí àwọn ìlànà wọ́n sì da majẹmu ayérayé. Nítorí náà ègún ń pa ayé run lọ. Àwọn eniyan inú rẹ̀ ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, iná ń jó àwọn olùgbé inú rẹ̀, eniyan díẹ̀ ni ó sì kù. Ọtí waini ń ṣọ̀fọ̀. Igi èso àjàrà ń joró, gbogbo àwọn tí ń ṣe àríyá ti ń kẹ́dùn. Ìró ìlù ayọ̀ ti dákẹ́, ariwo àwọn alárìíyá ti dópin. Àwọn tí ń tẹ dùùrù ti dáwọ́ dúró. Wọn kò mu ọtí níbi tí wọ́n ti ń kọrin mọ́ ọtí líle sì korò lẹ́nu àwọn tí ń mu ún. Ìlú ìdàrúdàpọ̀ ti wó palẹ̀, ó ti dòfo, gbogbo ìlẹ̀kùn ilé ti tì, kò sì sí ẹni tí ó lè wọlé. Ariwo ta lóde nítorí kò sí ọtí waini, oòrùn ayọ̀ ti wọ̀; ayọ̀ di àwátì ní ilẹ̀ náà. Gbogbo ìlú ti di ahoro, wọ́n ti wó ẹnu ibodè ìlú wómúwómú. Bẹ́ẹ̀ ní yóo rí ní ilẹ̀ ayé, láàrin àwọn orílẹ̀-èdè bí igi olifi tí a ti gbọn gbogbo èso rẹ̀ sílẹ̀, lẹ́yìn tí a ti kórè tán ninu ọgbà àjàrà. Wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n ń kọrin ayọ̀, wọ́n ń yin OLUWA lógo láti ìhà ìwọ̀-oòrùn wá. Nítorí náà ẹ fi ògo fún OLUWA ní ìhà ìlà-oòrùn; ẹ̀yin tí ń gbé etí òkun, ẹ fògo fún OLUWA Ọlọrun Israẹli. Láti òpin ayé ni a ti ń gbọ́ ọpọlọpọ orin ìyìn, wọ́n ń fi ògo fún Olódodo. Ṣugbọn èmi sọ pé: “Mò ń rù, mò ń joro, mò ń joro, mo gbé! Nítorí pé àwọn ọ̀dàlẹ̀ ń dalẹ̀, wọ́n ń dalẹ̀, wọ́n ń hùwà àgàbàgebè.” Ẹ̀rù ati kòtò, ati tàkúté ń bẹ níwájú yín ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ ayé. Ẹni tí ẹ̀rù bá bà tí ó sá, yóo já sinu kòtò, ẹni tí ó bá rá pálá jáde ninu kòtò yóo kó sinu tàkúté. Nítorí pé àwọn fèrèsé ojú ọ̀run ti ṣí, àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé sì mì tìtì. Ayé ti fọ́, ayé ti fàya, ayé sì mì tìtì. Ayé ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n bí ọ̀mùtí, ó ń mì bí abà oko. Ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wọ̀ ọ́ lọ́rùn, ó wó lulẹ̀, kò ní dìde mọ́. Ní àkókò náà, OLUWA yóo fìyà jẹ àwọn ogun ọ̀run, lọ́run; ati àwọn ọba ayé, lórí ilẹ̀ ayé. A óo gbá gbogbo wọn jọ pọ̀ sinu kòtò bí ẹlẹ́wọ̀n, wọn óo wà ní àtìmọ́lé ninu ẹ̀wọ̀n. Lẹ́yìn ọpọlọpọ ọjọ́, a óo fìyà jẹ wọ́n. Òṣùpá yóo dààmú, ìtìjú yóo sì bá oòrùn. Nítorí OLUWA àwọn ọmọ-ogun yóo jọba lórí òkè Sioni ati ní Jerusalẹmu. Yóo sì fi ògo rẹ̀ hàn níwájú àwọn àgbààgbà wọn. OLUWA, ìwọ ni Ọlọrun mi. N óo gbé ọ ga: n óo yin orúkọ rẹ. Nítorí pé o ti ṣe àwọn nǹkan ìyanu, o ti ṣe àwọn ètò láti ìgbà àtijọ́, o mú wọn ṣẹ pẹlu òtítọ́. O sọ àwọn ìlú di òkítì àlàpà o sì ti pa àwọn ìlú olódi run. O wó odi gíga àwọn àjèjì, kúrò lẹ́yìn ìlú, ẹnikẹ́ni kò sì ní tún un kọ́ mọ́. Nítorí náà àwọn alágbára yóo máa yìn ọ́ ìlú àwọn orílẹ̀-èdè aláìláàánú yóo bẹ̀rù rẹ. Nítorí pé ìwọ ni ibi ìsádi fún talaka, ibi ìsápamọ́sí fún aláìní lákòókò ìṣòro. Ìwọ ni ibi ààbò nígbà òjò, ati ìbòòji ninu oòrùn. Nítorí bí ìjì ti rí lára ògiri bẹ́ẹ̀ ni ibinu aláìláàánú rí; ó dàbí ooru ninu aṣálẹ̀. O pa àwọn àjèjì lẹ́nu mọ́; bí òjìji ìkùukùu tií sé ooru mọ́, bẹ́ẹ̀ ni o ṣe dá orin mọ́ àwọn oníjàgídíjàgan lẹ́nu. OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo fi àwọn ẹran ọlọ́ràá se àsè kan fún gbogbo orílẹ̀-èdè; yóo pa àwọn ẹran àbọ́pa, pẹlu ọtí waini, ẹran àbọ́pa tí ó sanra, tí ó kún fún mùdùnmúdùn, ati ọtí waini tí ó dára. Lórí òkè yìí, OLUWA yóo fa aṣọ tí a ta bo àwọn eniyan lójú ya, àní aṣọ tí a dà bo gbogbo orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀. Yóo gbé ikú mì títí lae, OLUWA yóo nu omijé nù kúrò lójú gbogbo eniyan. Yóo mú ẹ̀gàn àwọn eniyan rẹ̀ kúrò, ní gbogbo ilẹ̀ ayé. OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. Wọn óo máa wí ní ọjọ́ náà pé, “Ọlọrun wa nìyí; a ti ń dúró dè é kí ó lè gbà wá, OLUWA nìyí; òun ni a ti ń dúró dè. Ẹ jẹ́ kí á máa yọ̀, kí inú wa sì dùn nítorí ìgbàlà rẹ̀.” Nítorí OLUWA yóo na ọwọ́ ààbò rẹ̀ sórí òkè yìí. Ṣugbọn àwọn ará Moabu yóo di àtẹ̀mọ́lẹ̀ lórí ilẹ̀ wọ́n, bíi koríko tí a tẹ̀ mọ́lẹ̀ lórí ààtàn. Wọn óo na ọwọ́ ní ààrin rẹ̀ bí ìgbà tí ẹni tí ń lúwẹ̀ẹ́ bá nawọ́ ninu omi. Ṣugbọn OLUWA yóo rẹ ìgbéraga wọn sílẹ̀, ọwọ́ wọn yóo sì rọ. OLUWA yóo bi odi gíga rẹ̀ wó, yóo wó o palẹ̀, yóo sì sọ ọ́ di erùpẹ̀ ilẹ̀. Ní àkókò náà, orin tí wọn óo máa kọ ní ilẹ̀ Juda ni pé: “A ní ìlú tí ó lágbára, ó fi ìgbàlà ṣe odi ati ibi ààbò. Ẹ ṣí ìlẹ̀kùn ibodè, kí orílẹ̀-èdè olódodo, tí ń ṣe òtítọ́ lè wọlé. O óo pa àwọn tí wọ́n gbé ọkàn wọn lé ọ mọ́ ní alaafia pípé, nítorí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọ. Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA títí lae, nítorí àpáta ayérayé ni OLUWA Ọlọrun. Ó sọ àwọn tí ń gbé orí òkè kalẹ̀, ó sọ ìlú tí ó wà ní orí òkè téńté di ilẹ̀, ó sọ ọ́ di ilẹ̀ patapata, ó fà á sọ sinu eruku. Wọ́n ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, bí àwọn òtòṣì tí ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni àwọn aláìní ń tẹ̀ ẹ́.” Ọ̀nà títẹ́jú ni ọ̀nà àwọn olódodo ó mú kí ọ̀nà àwọn olódodo máa dán. Àwa dúró dè ọ́ ní ọ̀nà ìdájọ́ rẹ, OLUWA, orúkọ rẹ ati ìrántí rẹ ni ọkàn wa ń fẹ́. Ọkàn mi ń ṣe àfẹ́rí rẹ lálẹ́, mo sì ń fi tọkàntọkàn wá ọ nítorí nígbà tí ìlànà rẹ bá wà láyé ni àwọn ọmọ aráyé yóo kọ́ òdodo. Bí a bá ṣàánú ẹni ibi, kò ní kọ́ láti ṣe rere. Yóo máa ṣe ibi ní ilẹ̀ àwọn olódodo, kò sì ní rí ọlá ńlá OLUWA. OLUWA o ti gbé ọwọ́ rẹ sókè láti jẹ àwọn ọ̀tá níyà, ṣugbọn wọn kò rí i. Jẹ́ kí wọn rí i pé ọ̀rọ̀ àwọn eniyan rẹ jẹ ọ́ lógún, kí ojú sì tì wọ́n. Jẹ́ kí iná tí o dá fún àwọn ọ̀tá rẹ jó wọn run. OLUWA ìwọ yóo fún wa ní alaafia, nítorí pé ìwọ ni o ṣe gbogbo iṣẹ́ wa fún wa. OLUWA, Ọlọrun wa, àwọn oluwa mìíràn ti jọba lórí wa ṣugbọn orúkọ rẹ nìkan ni àwa mọ̀. Wọ́n ti kú, wọn kò ní wà láàyè mọ́, ẹ̀mí wọn kò ní dìde mọ́ ní isà òkú. Nítorí bẹ́ẹ̀ ni o ṣe jẹ wọ́n níyà, o sì pa wọ́n run, o sì ti sọ gbogbo ìrántí wọn di ohun ìgbàgbé. Ṣugbọn ìwọ OLUWA ti mú kí orílẹ̀-èdè náà pọ̀ sí i, OLUWA, o ti bukun orílẹ̀-èdè náà, gbogbo ààlà ilẹ̀ náà ni o ti bì sẹ́yìn, o sì ti buyì kún ara rẹ. OLUWA nígbà tí wọ́n wà ninu ìpọ́njú, wọ́n wá ọ, wọ́n fọkàn gbadura nígbà tí o jẹ wọ́n ní ìyà. Bí aboyún tí ó fẹ́ bímọ, tí ó ń yí, tí ó sì ń ké ìrora, nígbà tí àkókò àtibímọ rẹ̀ súnmọ́ tòsí bẹ́ẹ̀ ni a rí nítorí rẹ, OLUWA. A wà ninu oyún, ara ń ro wá, a ní kí a bí, òfo ló jáde. A kò ṣẹgun ohunkohun láyé bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń gbé ayé kò tíì ṣubú. Àwọn òkú wa yóo jí, wọn óo dìde kúrò ninu ibojì. Ẹ tají kí ẹ máa kọrin, ẹ̀yin tí ó sùn ninu erùpẹ̀. Nítorí pé ìrì ìmọ́lẹ̀ ni ìrì yín, ẹ óo sì sẹ ìrì náà sì ilẹ̀ àwọn òkú. Ẹ gbéra nílẹ̀, ẹ̀yin eniyan mi, ẹ wọ inú yàrá yín, kí ẹ sì ti ìlẹ̀kùn mọ́rí; ẹ farapamọ́ fún ìgbà díẹ̀, títí tí ibinu OLUWA yóo fi kọjá. OLUWA óo yọ láti ibùgbé rẹ̀, láti fi ìyà jẹ àwọn tí ń gbé inú ayé, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ilẹ̀ yóo tú ẹ̀jẹ̀ àwọn tí wọ́n pa sórí rẹ̀ jáde, kò sì ní bo àwọn tí a pa mọ́lẹ̀ mọ́. Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo fi idà rẹ̀ tí ó mú, tí ó tóbi, tí ó sì lágbára, pa Lefiatani, ejò tí ó ń fò, Lefiatani, ejò tí ń lọ́ wérékéké, yóo sì pa ejò ńlá tí ń bẹ ninu òkun. Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo kọrin nípa ọgbà àjàrà dáradára kan pé, “Èmi OLUWA ni olùṣọ́ rẹ̀, lásìkò, lásìkò ni mò ń bomi rin ín; tọ̀sán-tòru ni mò ń ṣọ́ ọ kí ẹnìkan má baà bà á jẹ́. Inú kò bí mi, ǹ bá rí ẹ̀gún ati pàǹtí ninu rẹ̀, ǹ bá gbógun tì wọ́n, ǹ bá jó gbogbo wọn níná papọ̀. Ṣugbọn bí wọn bá fi mí ṣe ààbò, kí wọn wá kí á parí ìjà láàrin ara wa; kí wọn wá kí á parí ìjà láàrin ara wa.” Ní ọjọ́ iwájú Jakọbu yóo ta gbòǹgbò, Israẹli yóo tanná, yóo rúwé, yóo so, èso rẹ̀ yóo sì kún gbogbo ayé. Ṣé OLUWA ti jẹ wọ́n níyà bí ó ti fìyà jẹ àwọn tí ó jẹ wọ́n níyà? Ṣé ó ti pa wọ́n bí ó ti pa àwọn tí ó pa wọ́n? OLUWA fìyà jẹ àwọn eniyan rẹ̀, ó kó wọn lọ sí ìgbèkùn; ó lé wọn jáde ní ìlú, bí ìgbà tí ẹ̀fúùfù líle bá ń fẹ́ láti ìlà oòrùn. Ọ̀nà tí a fi lè pa ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu rẹ́, tí a fi lè mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kúrò ni pé: Kí ó fọ́ gbogbo òkúta àwọn pẹpẹ oriṣa rẹ̀ túútúú, bí ẹfun tí a lọ̀ kúnná; kí ó má ku ère oriṣa Aṣera tabi pẹpẹ turari kan lóòró. Nítorí ìlú olódi ti di ahoro, ó di ibùgbé tí a kọ̀ sílẹ̀, tí a sì patì bí aginjù; ibẹ̀ ni àwọn ọmọ mààlúù yóo ti máa jẹko, wọn óo dùbúlẹ̀ níbẹ̀, wọn óo sì máa jẹ àwọn ẹ̀ka igi rẹ̀. Àwọn ẹ̀ka igi náà yóo dá nígbà tí wọ́n bá gbẹ, àwọn obinrin yóo sì fi wọ́n dáná. Nítorí òye kò yé àwọn eniyan wọnyi rárá; nítorí náà, ẹni tí ó dá wọn kò ní ṣàánú wọn, Ẹni tí ó mọ wọ́n kò ní yọ́nú sí wọn. Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo pa ẹ̀yin eniyan Israẹli bí ẹni pa ọkà, láti odò Yufurate títí dé odò Ijipti, yóo sì ko yín jọ lọ́kọ̀ọ̀kan. Ní ọjọ́ náà, a óo fun fèrè ogun ńlá, àwọn tí ó ti sọnù sí ilẹ̀ Asiria ati àwọn tí a lé lọ sí ilẹ̀ Ijipti yóo wá sin OLUWA lórí òkè mímọ́ ní Jerusalẹmu. Adé ìgbéraga àwọn ọ̀mùtí Efuraimu gbé! Ẹwà ògo rẹ̀ tí ń ṣá bí ìtànná náà gbé! Ìlú tí ó wà ní òkè àfonífojì dáradára, ohun àmúyangàn fún àwọn tí ó mutí yó. Wò ó! OLUWA ní ẹnìkan, tí ó lágbára bí ẹ̀fúùfù líle, ati bí ìjì apanirun, bí afẹ́fẹ́ òjò tí ó lágbára tí àgbàrá rẹ̀ ṣàn kọjá bèbè; ẹni náà yóo bì wọ́n lulẹ̀. Ẹsẹ̀ ni yóo fi tẹ adé ìgbéraga àwọn ọ̀mùtí ilẹ̀ Efuraimu. Ògo rẹ̀ tí ń ṣá bí òdòdó tí ó wà ní òkè àfonífojì dáradára, yóo dàbí àkọ́so èso ọ̀pọ̀tọ́, tí ó pọ́n ṣáájú ìgbà ìkórè. Ẹni tó bá rí i yóo sáré sí i, yóo ká a, yóo sì jẹ ẹ́. Ní ọjọ́ náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo jẹ́ adé ògo ati adé ẹwà, fún àwọn tí ó kù ninu àwọn eniyan rẹ̀. Yóo jẹ́ ẹ̀mí ìdájọ́ ẹ̀tọ́ fún adájọ́ tí ó jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́, yóo jẹ́ agbára fún àwọn tí ó ń lé ogun sẹ́yìn lẹ́nu ibodè. Ọtí waini ń ti àwọn wọnyi, ọtí líle ń mú wọn ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n. Ọtí líle ń ti alufaa ati wolii, ọtí waini kò jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí wọ́n ń ṣe mọ́. Ọtí líle ń mú wọn ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n; wọ́n ń ríran èké, wọ́n ń dájọ́ irọ́. Nítorí èébì kún orí gbogbo tabili oúnjẹ, gbogbo ilẹ̀ sì kún fún ìdọ̀tí Wọ́n ń sọ pé, “Ta ni yóo kọ́ lọ́gbọ́n? Ta sì ni yóo jíṣẹ́ náà fún? Ṣé àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọyàn lẹ́nu wọn, àbí àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ já lẹ́nu ọmú? Nítorí pé gbogbo rẹ̀ tòfin-tòfin ni, èyí òfin, tọ̀hún ìlànà. Díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn-ún.” Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn àjèjì tí èdè wọn yàtọ̀ ni OLUWA yóo lò láti bá àwọn eniyan wọnyi sọ̀rọ̀. Àwọn tí ó ti wí fún pé: Ìsinmi nìyí, ẹ fún àwọn tí àárẹ̀ mú ní ìsinmi; ìtura nìyí. Sibẹsibẹ wọ́n kọ̀, wọn kò gbọ́. Nítorí náà ọ̀rọ̀ OLUWA sí wọn yóo jẹ́ tòfin-tòfin, èyí òfin tọ̀hún ìlànà. Díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn-ún, kí wọ́n baà lè lọ ṣubú sẹ́yìn kí wọ́n sì fọ́ wẹ́wẹ́; kí á lè dẹ tàkúté sílẹ̀ fún wọn, kí ọwọ́ lè tẹ̀ wọ́n. Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí, ẹ̀yin oníyẹ̀yẹ́ eniyan, tí ẹ̀ ń ṣe àkóso àwọn eniyan wọnyi ní Jerusalẹmu. Nítorí ẹ wí pé: “A ti bá ikú dá majẹmu, a sì ti bá ibojì ṣe àdéhùn. Nígbà tí jamba bá ń bọ̀, kò ní dé ọ̀dọ̀ wa; nítorí a ti fi irọ́ ṣe ibi ìsádi wa, a sì ti fi èké ṣe ibi ààbò.” Nítorí náà OLUWA Ọlọrun sọ pé, “Wò ó! Èmi yóo ri òkúta ìpìlẹ̀ ilé kan mọ́lẹ̀ ní Sioni, yóo jẹ́ òkúta tí ó lágbára, òkúta igun ilé iyebíye, tí ó ní ìpìlẹ̀ tí ó dájú: Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, ojú kò níí kán an. Ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ni n óo fi ṣe okùn ìwọnlẹ̀, òdodo ni n óo fi ṣe ìwọ̀n ògiri.” Òjò àdàpọ̀ mọ́ yìnyín yóo gbá ibi ààbò irọ́ dànù, omi yóo sì bo ibi tí wọ́n sápamọ́ sí. Majẹmu tí ẹ bá ikú dá yóo wá di òfo, àdéhùn yín pẹlu ibojì yóo sì di asán. Nígbà tí jamba bá ń ṣẹlẹ̀ káàkiri, yóo máa dé ba yín. Gbogbo ìgbà tí ó bá ti ń ṣẹlẹ̀ ni yóo máa ba yín tí yóo máa gba yín lọ. Yóo máa ṣẹlẹ̀ láàárọ̀, yóo sì máa ṣẹlẹ̀ tọ̀sán-tòru. Ẹ̀rù yóo ba eniyan, tí eniyan bá mọ ìtumọ̀ ìkìlọ̀ náà. Ibùsùn kò ní na eniyan tán. Bẹ́ẹ̀ ni aṣọ ìbora kò ní fẹ̀ tó eniyan bora. Nítorí pé OLUWA yóo dìde bí ó ti ṣe ní òkè Firasi, yóo bínú bí ó ti bínú ní àfonífojì Gibeoni. Yóo ṣe ohun tí ó níí ṣe, ohun tí yóo ṣe yóo jọni lójú; yóo ṣe iṣẹ́ rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ yóo ṣe àjèjì. Nítorí náà ẹ má ṣe yẹ̀yẹ́, kí á má baà so ẹ̀wọ̀n yín le. Nítorí mo ti gbọ́ ìkéde ìparun, tí OLUWA àwọn ọmọ ogun pinnu láti mú wá sórí ilẹ̀ ayé. Ẹ fetí sílẹ̀ kí ẹ gbọ́ ohùn mi, ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, ṣé ẹni tí ń kọ ilẹ̀ tí ó fẹ́ gbin ohun ọ̀gbìn lè máa kọ ọ́ lọ láì dáwọ́ dúró? Àbí ó lè máa kọ ebè lọ láì ní ààlà? Ṣugbọn bí ó bá ti tọ́jú oko rẹ̀ tán, ṣé kò ní fọ́n èso dili ati èso Kumini sinu rẹ̀, kí ó gbin alikama lẹ́sẹẹsẹ; kí ó gbin ọkà baali sí ibi tí ó yẹ, kí ó sì gbin oríṣìí ọkà mìíràn sí ààlà oko rẹ̀? Yóo ṣe iṣẹ́ rẹ̀ létòlétò bí ó ti yẹ, nítorí pé Ọlọrun rẹ̀ ní ń kọ́ ọ. Àgbẹ̀ kì í fi òkúta ńlá ṣẹ́ ẹ̀gúsí, bẹ́ẹ̀ ni kò ní fi kùmọ̀, lu kumini. Ọ̀pá ni wọ́n fí ń lu ẹ̀gúsí; igi lásán ni wọ́n fí ń lu kumini. Ǹjẹ́ eniyan a máa fi kùmọ̀ lọ ọkà alikama tí wọ́n fi ń ṣe burẹdi? Rárá, ẹnìkan kì í máa pa ọkà títí kí ó má dáwọ́ dúró. Bó ti wù kí eniyan fi ẹṣin yí ẹ̀rọ ìpakà lórí ọkà alikama tó, ẹ̀rọ ìpakà kò lè lọ ọkà kúnná. Ọ̀dọ̀ OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ìmọ̀ yìí ti ń wá pẹlu, ìmọ̀ràn rẹ̀ yani lẹ́nu; ọgbọ́n rẹ̀ ni ó sì ga jùlọ. Ó ṣe fún Arieli, Jerusalẹmu, ìlú tí ń jẹ́ pẹpẹ Ọlọrun! Ìlú tí Dafidi pàgọ́ sí. Ẹ ṣe ọdún kan tán, ẹ tún ṣe òmíràn sí i, ẹ máa ṣe àwọn àjọ̀dún ní gbogbo àkókò wọn. Sibẹsibẹ n óo mú ìpọ́njú bá ìlú tí ń jẹ́ pẹpẹ Ọlọrun. Ìkérora ati ìpohùnréré ẹkún yóo wà ninu rẹ̀, bíi Arieli ni yóo sì rí sí mi. N óo jẹ́ kí ogun dó tì yín yíká n óo fi àwọn ilé ìṣọ́ ka yín mọ́; n óo sì mọ òkítì sára odi yín. Ninu ọ̀gbun ilẹ̀ ni a óo ti máa gbóhùn rẹ̀, láti inú erùpẹ̀ ni a óo ti máa gbọ́, tí yóo máa sọ̀rọ̀. A óo máa gbọ́ ohùn rẹ̀ láti inú ilẹ̀ bí ohùn òkú, a óo sì máa gbọ́ tí yóo máa sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ láti inú erùpẹ̀. Àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóo pọ̀ bí iyanrìn, ogunlọ́gọ̀ àwọn aláìláàánú yóo bò ọ́ bí ìyàngbò tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ. Lójijì, kíá, OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo dé ba yín, pẹlu ààrá, ati ìdágìrì, ati ariwo ńlá; ati ààjà, ati ìjì líle, ati ahọ́n iná ajónirun. Ogunlọ́gọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí ń bá ìlú tí ń jẹ́ pẹpẹ Ọlọrun jà, yóo parẹ́ bí àlá, gbogbo àwọn tí ń bá ìlú olódi rẹ jà, tí wọn ń ni í lára yóo parẹ́ bí ìran òru. Bí ìgbà tí ẹni tí ebi ń pa bá lá àlá pé òun ń jẹun, tí ó jí, tí ó rí i pé ebi sì tún pa òun, tabi tí ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ́ lá àlá pé òun ń mu omi ṣugbọn tí ó jí, tí ó rí i pé òùngbẹ ṣì ń gbẹ òun, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún ogunlọ́gọ̀ orílẹ̀-èdè tí ń bá Jerusalẹmu jà. Ẹ sọ ara yín di òmùgọ̀, kí ẹ sì máa ṣe bí òmùgọ̀. Ẹ fọ́ ara yín lójú kí ẹ sì di afọ́jú. Ẹ mu àmuyó, ṣugbọn kì í ṣe ọtí. Ẹ máa ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n láì mu ọtí líle. Nítorí OLUWA ti fi ẹ̀mí oorun àsùnwọra si yín lára Ó ti di ẹ̀yin wolii lójú; ó ti bo orí ẹ̀yin aríran. Gbogbo ìran yìí sì ru yín lójú, bí ọ̀rọ̀ inú ìwé tí a fi èdìdì dì. Nígbà tí wọ́n gbé e fún ọ̀mọ̀wé tí wọ́n ní, “Jọ̀wọ́ bá wa kà á.” Ó ní òun kò lè kà á nítorí pé wọ́n ti fi èdìdì dì í. Nígbà tí wọ́n gbé e fún ẹni tí kò mọ̀wé tí wọ́n ní, “Jọ̀wọ́ bá wa kà á.” Ó ní òun kò mọ̀wé kà. OLUWA ní, “Nítorí pé ẹnu nìkan ni àwọn eniyan wọnyi fi ń súnmọ́ mi, ètè lásán ni wọ́n sì fi ń yìn mí; ṣugbọn ọkàn wọn jìnnà sí mi. Òfin eniyan, tí wọn kọ́ sórí lásán, ni ìbẹ̀rù mi sì jẹ́ fún wọn. Nítorí náà n óo tún ṣe ohun ìyanu sí àwọn eniyan wọnyi, ohun ìyanu tí ó jọni lójú. Ọgbọ́n yóo parẹ́ mọ́ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ninu, ìmọ̀ràn yóo sì parẹ́ mọ́ àwọn ọ̀mọ̀ràn níkùn.” Àwọn tí wọ́n fi èrò wọn pamọ́ fún OLUWA gbé; àwọn tí iṣẹ́ wọn jẹ́ iṣẹ́ òkùnkùn, tí ń wí pé, “Ta ló rí wa? Ta ló mọ̀ wá?” Ẹ dorí gbogbo nǹkan kodò. Ṣé eniyan lè sọ amọ̀kòkò di amọ̀? Kí nǹkan tí eniyan ṣe, wí nípa ẹni tí ó ṣe é pé: “Kìí ṣe òun ló ṣe mí.” Tabi kí nǹkan tí eniyan dá sọ nípa ẹni tí ó dá a pé: “Kò ní ìmọ̀.” Ṣebí díẹ̀ ṣínún ló kù tí a óo sọ Lẹbanoni di ọgbà igi eléso a óo sì máa pe ọgbà igi eléso náà ní igbó. Ní ọjọ́ náà, odi yóo gbọ́ ohun tí a kọ sinu ìwé, ojú afọ́jú yóo ríran, ninu òkùnkùn biribiri rẹ̀. Àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóo tún láyọ̀ láti ọ̀dọ̀ OLUWA. Àwọn aláìní yóo máa yọ̀ ninu Ẹni Mímọ́ Israẹli nítorí pé àwọn aláìláàánú yóo di asán, àwọn apẹ̀gàn yóo di òfo; àwọn tí ń wá ọ̀nà láti ṣe ibi yóo parun; àwọn tí ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu sọ eniyan di ẹlẹ́ṣẹ̀, tí ń dẹ tàkúté sílẹ̀ fún ẹni tí ń tọ́ni sọ́nà, tí wọ́n sì ń fi àbòsí tí kò nídìí ti olódodo sí apá kan. Nítorí náà, OLUWA tí ó ra Abrahamu pada sọ nípa ilé Jakọbu pé, “Ojú kò ní ti Jakọbu mọ́ bẹ́ẹ̀ ni ojú rẹ̀ kò ní rẹ̀wẹ̀sì mọ́. Nítorí nígbà tí ó bá rí àwọn ọmọ rẹ̀, tíí ṣe iṣẹ́ ọwọ́ mi láàrin wọn, wọn óo fi ọ̀wọ̀ fún orúkọ mi. Wọn óo bọ̀wọ̀ fún Ẹni Mímọ́ Jakọbu; wọn óo sì bẹ̀rù Ọlọrun Israẹli. Àwọn tí ó ti ṣìnà ninu ẹ̀mí yóo ní òye; àwọn tí ń kùn yóo sì gba ẹ̀kọ́.” OLUWA ní: “Àwọn ọmọ aláìgbọràn gbé. Àwọn tí wọn ń dá àbá tí ó yàtọ̀ sí tèmi, tí wọn ń kó ẹgbẹ́ jọ, ṣugbọn tí kìí ṣe nípa ẹ̀mí mi; kí wọ́n lè máa dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀. Wọ́n múra, wọ́n gbọ̀nà Ijipti láì bèèrè ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ mi. Wọ́n lọ sápamọ́ sí abẹ́ ààbò Farao, wọ́n lọ wá ààbò ní Ijipti. Nítorí náà, ààbò Farao yóo di ìtìjú fún wọn, ibi ìpamọ́ abẹ́ Ijipti yóo di ìrẹ̀sílẹ̀ fún wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn olórí wọn ti lọ sí Soani, tí àwọn ikọ̀ wọn sì ti dé Hanesi. Ojú yóo tì wọ́n, nítorí wọn ń wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn tí kò lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Wọn kò lè rí ìrànwọ́ tabi anfaani kankan níbẹ̀, bíkòṣe ìtìjú ati ẹ̀gàn.” Àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ẹranko ilẹ̀ Nẹgẹbu nìyí: “Wọ́n di àwọn nǹkan ìní wọn sí ẹ̀yìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, wọ́n sì di ìṣúra wọn sí ẹ̀yìn ràkúnmí. Wọ́n ń la ilẹ̀ ìṣòro ati wahala kọjá. Ilẹ̀ àwọn akọ kinniun ati abo kinniun, ilẹ̀ paramọ́lẹ̀ ati ejò amúbíiná tí ń fò. Wọ́n ń lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan tí kò lè ṣe wọ́n ní anfaani. Nítorí ìmúlẹ̀mófo ni ìrànwọ́ Ijipti. Nítorí náà ni mo ṣe pè é ní, ‘Rahabu tí ń jókòó lásán.’ ” Nisinsinyii lọ kọ ọ́ sílẹ̀ níwájú wọn, kí o sì kọ ọ́ sinu ìwé, kí ó lè wà títí di ẹ̀yìn ọ̀la, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí títí lae; nítorí aláìgbọràn eniyan ni wọ́n, Òpùrọ́ ọmọ tí kìí fẹ́ gbọ́ ìtọ́ni OLUWA. Wọ́n á máa sọ fún àwọn aríran pé, “Ẹ má ríran mọ.” Wọ́n á sì máa sọ fún àwọn wolii pé, “Ẹ má sọ àsọtẹ́lẹ̀ òtítọ́ fún wa mọ́, ọ̀rọ̀ dídùn ni kí ẹ máa sọ fún wa, kí ẹ sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ ẹ̀tàn fún wa. Ẹ fi ojú ọ̀nà sílẹ̀, ẹ yà kúrò lójú ọ̀nà, ẹ má sọ nípa Ẹni Mímọ́ Israẹli fún wa mọ́.” Nítorí náà, Ẹni Mímọ́ Israẹli ní: “Nítorí pé ẹ kẹ́gàn ọ̀rọ̀ yìí, ẹ gbẹ́kẹ̀lé ìninilára ati ẹ̀tàn, ẹ sì gbára lé wọn, nítorí náà, ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ̀ ń dá yìí; yóo dàbí ògiri gíga tí ó là, tí ó sì fẹ́ wó; lójijì ni yóo wó lulẹ̀ lẹ́ẹ̀kanṣoṣo. Wíwó rẹ̀ yóo dàbí ìgbà tí eniyan la ìkòkò mọ́lẹ̀, tí ó fọ́ yángá-yángá, tóbẹ́ẹ̀ tí eniyan kò rí àpáàdì kan mú jáde ninu rẹ̀, tí a lè fi fọn iná ninu ààrò, tabi èkúfọ́, tí a lè fi bu omi ninu odò.” Nítorí OLUWA Ọlọrun, Ẹni Mímọ́ Israẹli ní: “Bí ẹ bá yipada, tí ẹ sì farabalẹ̀, ẹ óo rí ìgbàlà; bí ẹ bá dákẹ́ jẹ́ẹ́ tí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun, ẹ óo lágbára. Ṣugbọn ẹ kọ̀. Ẹ sọ pé ó tì o, ẹ̀yin óo gun ẹṣin sálọ ni. Nítorí náà sísá ni ẹ óo sálọ. Ẹ sọ pé ẹṣin tí ó lè sáré ni ẹ óo gùn. Nítorí náà àwọn tí yóo máa le yín, wọn óo lè sáré gan-an ni. Ẹgbẹrun ninu yín yóo sá fún ẹyọ ọ̀tá yín kan, gbogbo yín yóo sì sá fún ẹyọ eniyan marun-un títí tí àwọn tí yóo kú ninu yín yóo fi dàbí igi àsíá lórí òkè. Wọn óo dàbí àsíá ati àmì lórí òkè.” Nítorí náà OLUWA ń dúró dè yín, ó ti ṣetán láti ṣàánú yín. Yóo dìde, yóo sì ràn yín lọ́wọ́. Nítorí Ọlọrun Olódodo ni OLUWA. Ẹ̀yin ará Sioni tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, ẹ kò ní sọkún mọ́. OLUWA yóo ṣàánú yín nígbà tí ẹ bá ké pè é, yóo sì da yín lóhùn nígbà tí ó bá gbọ́ igbe yín. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA yóo jẹ́ kí ẹ ní ọpọlọpọ ìṣòro, yóo sì jẹ́ kí ẹ ṣe ọpọlọpọ wahala, sibẹsibẹ olùkọ́ yín kò ní farapamọ́ fun yín mọ́, ṣugbọn ẹ óo máa fi ojú yín rí i. Bí ẹ bá fẹ́ yapa sí apá ọ̀tún tabi apá òsì, ẹ óo máa gbọ́ ohùn kan lẹ́yìn yín tí yóo máa wí pé, “Ọ̀nà nìyí, ibí ni kí ẹ gbà.” Àwọn oriṣa tí ẹ yọ́ fadaka bò, ati àwọn ère tí ẹ yọ́ wúrà bò yóo di nǹkan èérí lójú yín. Ẹ óo kọ̀ wọ́n sílẹ̀ bí nǹkan aláìmọ́. Ẹ óo sì wí fún wọn pé, “Ẹ pòórá!” OLUWA yóo sì fi òjò ibukun sí orí èso tí ẹ gbìn sinu oko, nǹkan ọ̀gbìn yín yóo sì so lọpọlọpọ. Ní àkókò náà, àwọn ẹran ọ̀sìn yín tí yóo máa jẹ ní pápá oko yóo pọ̀. Àwọn mààlúù ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ẹ fí ń ṣe iṣẹ́ lóko yóo máa jẹ oko tí a fi iyọ̀ sí; tí a ti gbọn ìdọ̀tí kúrò lára rẹ̀. Omi yóo máa ṣàn jáde láti orí gbogbo òkè gíga ati gbogbo òkè ńlá, ní ọjọ́ tí ọpọlọpọ yóo kú, nígbà tí ilé ìṣọ́ bá wó lulẹ̀. Òṣùpá yóo mọ́lẹ̀ bí oòrùn; oòrùn yóo mọ́lẹ̀ ní ìlọ́po meje, ní ọjọ́ tí OLUWA yóo bá di ọgbẹ́ àwọn eniyan rẹ̀, tí yóo sì wo ọgbẹ́ tí ó dá sí wọn lára sàn. Ẹ wo OLUWA tí ń bọ̀ láti ilẹ̀ òkèèrè, ó ń bọ̀ tìbínú-tìbínú; ninu èéfín ńlá tí ń lọ sókè. Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ kún fún ibinu; ahọ́n rẹ̀ dàbí iná tí ń jóni run. Èémí rẹ̀ dàbí odò tí ó ṣàn kọjá bèbè rẹ̀ tí ó lè mu eniyan dé ọrùn. Yóo fi ajọ̀ ìparun jọ àwọn orílẹ̀-èdè, yóo sì fi ìjánu tí ń múni ṣìnà bọ àwọn eniyan lẹ́nu. Ẹ óo kọ orin kan bí orin alẹ́ ọjọ́ àjọ̀dún mímọ́, inú yín yóo sì dùn bíi ti ẹni tí ń jó ijó fèrè lọ sórí òkè OLUWA, àpáta Israẹli. OLUWA yóo jẹ́ kí ẹ gbọ́ ohùn rẹ̀ tí ó lógo, yóo sì jẹ́ kí ẹ rí ọwọ́ rẹ̀ tí yóo fà yọ pẹlu ibinu ńlá ati ninu iná ajónirun; pẹlu ẹ̀fúùfù ati ìjì líle ati òjò yìnyín. Ìbẹ̀rù-bojo yóo mú àwọn ará Asiria nígbà tí wọ́n bá gbóhùn OLUWA, nígbà tí ó bá fi kùmọ̀ rẹ̀ lù wọ́n. Ìró ọ̀pá tí OLUWA yóo fi nà wọ́n yóo dàbí ìró aro ati dùùrù. OLUWA yóo dojú ogun kọ wọ́n. Nítorí pé a ti pèsè iná ìléru sílẹ̀ láti ìgbà àtijọ́ fún ọba Asiria; iná ńlá tí ń jó pẹlu ọpọlọpọ igi. Èémí OLUWA tó dàbí ìṣàn imí-ọjọ́ ni yóo ṣá iná sí i. Àwọn tí ó ń lọ sí Ijipti fún ìrànlọ́wọ́ gbé! Àwọn tí wọ́n gbójú lé ẹṣin; tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé kẹ̀kẹ́ ogun nítorí pé wọ́n pọ̀, tí wọ́n gbójú lé ẹṣin nítorí pé wọ́n lágbára! Wọn kò gbójú lé Ẹni Mímọ́ Israẹli, wọn kò sì wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ OLUWA. Bẹ́ẹ̀ ni ó gbọ́n, ó sì mọ ọ̀nà tí ó fi lè mú kí àjálù dé bá eniyan, kì í sọ̀rọ̀ tán, kó yí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pada. Ṣugbọn yóo dìde sí ìdílé àwọn aṣebi, ati àwọn tí ń ti àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́yìn. Eniyan sá ni àwọn ará Ijipti, wọn kìí ṣe Ọlọrun. Ẹranko lásán sì ni ẹṣin wọn wọn kì í ṣe àǹjọ̀nnú. Bí OLUWA bá na ọwọ́, tí ó bá gbá wọn mú, ẹni tí ń ranni lọ́wọ́ yóo fẹsẹ̀ kọ, ẹni tí à ń ràn lọ́wọ́ yóo ṣubú; gbogbo wọn yóo sì jọ ṣègbé pọ̀. Nítorí OLUWA sọ fún mi pé, “Bí kinniun tabi ọmọ kinniun ti máa ń kùn lórí ẹran tí ó bá pa, tí kìí bìkítà fún igbe àwọn olùṣọ́ aguntan, tí wọ́n pera wọn jọ, tí wọn ń bọ̀, tí ẹ̀rù ariwo wọn kìí sìí bà á; bẹ́ẹ̀ ni OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo sọ̀kalẹ̀, yóo wá jà lórí òkè Sioni ati àwọn òkè tí ó yí Sioni ká. Bí àwọn ẹyẹ tií da ìyẹ́ bo ìtẹ́ wọn, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo dáàbò bo Jerusalẹmu, yóo dáàbò bò ó, yóo sì gbà á sílẹ̀ yóo dá a sí, yóo sì yọ ọ́ kúrò ninu ewu.” Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ pada sọ́dọ̀ ẹni tí ẹ ti ṣàìgbọràn sí lọpọlọpọ. Nítorí pé ní ọjọ́ náà, olukuluku yóo gbé àwọn ère fadaka ati ère wúrà tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe sọnù, àwọn ère tí ó mú wọn dẹ́ṣẹ̀. Idà ni yóo pa Asiria, ṣugbọn kì í ṣe láti ọwọ́ eniyan; idà tí kò ní ọwọ́ eniyan ninu ni yóo pa á run. Yóo sá lójú ogun, a óo sì kó àwọn ọmọkunrin rẹ̀ lọ máa ṣiṣẹ́ tipátipá. Ẹ̀rù yóo ba ọba Asiria, yóo sálọ. Ìpayà yóo mú kí àwọn ọ̀gágun rẹ̀ ju àsíá sílẹ̀. OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀, OLUWA tí iná rẹ̀ wà ní Sioni, tí ojú ààrò rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu. Wò ó! Ọba kan yóo jẹ pẹlu òdodo, àwọn ìjòyè yóo sì máa ṣe àkóso pẹlu ẹ̀tọ́. Olukuluku yóo dàbí ibi ààbò nígbà tí ẹ̀fúùfù bá ń fẹ́ ati ibi ìsásí nígbà tí ìjì bá ń jà Wọ́n óo dàbí odò ninu aṣálẹ̀, ati bí ìbòòji àpáta ńlá nílẹ̀ olóoru. Àwọn tí wọ́n bá rí i kò ní dijú sí i, etí àwọn tí ó gbọ́ ọ kò ní di. Àwọn tí kò ní àròjinlẹ̀ tẹ́lẹ̀ yóo ní òye, àwọn akólòlò yóo sì sọ̀rọ̀ ketekete. A kò ní máa pe aláìgbọ́n ní ọlọ́lá mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní máa pe abàlújẹ́ ní eniyan pataki. Nítorí pé aláìgbọ́n ń sọ̀rọ̀ òmùgọ̀, ọkàn rẹ̀ sì ń pète ibi. Ó ń ro bí yóo ṣe hùwà ẹni tí kò mọ Ọlọrun, tí yóo sọ̀rọ̀ ìsọkúsọ sí OLUWA; tí yóo fi ẹni tí ebi ń pa sílẹ̀, láì fún un ní oúnjẹ, tí yóo sì fi omi du ẹni òùngbẹ ń gbẹ. Kìkì ibi ni èrò inú àwọn eniyankeniyan. Wọn a máa pète ìkà, láti fi irọ́ pa àwọn talaka run, kì báà jẹ́ pé ẹjọ́ aláìní jàre. Ṣugbọn eniyan rere a máa ro èrò rere, ìdí nǹkan rere ni à á sì í bá wọn. Ẹ dìde, ẹ̀yin obinrin tí ara rọ̀, ẹ gbóhùn mi; ẹ̀yin ọmọbinrin tí ẹ wà ninu ìdẹ̀ra, ẹ tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi. Ní nǹkan bíi ọdún kan ó lé díẹ̀ sí i ẹ̀yin obinrin tí ẹ wà ninu ìdẹ̀ra; ẹ ó rí ìdààmú nítorí pé àkókò ìkórè yóo kọjá, èso àjàrà kò sì ní sí lórí igi mọ́. Ẹ gbọ̀n jìnnìjìnnì, ẹ̀yin obinrin tí ara rọ̀, kí wahala ba yín, ẹ̀yin tí ẹ wà ninu ìdẹ̀ra, ẹ tú aṣọ yín, kí ẹ wà ní ìhòòhò; kí ẹ sì ró aṣọ ọ̀fọ̀. Ẹ káwọ́ lérí, kí ẹ káàánú nítorí àwọn oko dáradára, ati nítorí àwọn àjàrà eléso; nítorí ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n ati ẹ̀gún ọ̀gàn ni ó ń hù lórí ilẹ̀ àwọn eniyan mi. Bákan náà, ẹ káàánú fún àwọn ilé aláyọ̀ ninu ìlú tí ó kún fún ayọ̀, nítorí pé àwọn eniyan yóo sá kúrò ní ààfin, ìlú yóo tú, yóo di ahoro. Òkè ati ilé ìṣọ́ yóo di ibùgbé àwọn ẹranko títí lae, yóo di ibi ìgbádùn fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́, ati pápá ibùjẹ fún àwọn ẹran ọ̀sìn. Bẹ́ẹ̀ ni nǹkan yóo rí, títí ẹ̀mí óo fi bà lé wa láti òkè ọ̀run wá títí aṣálẹ̀ yóo fi di ọgbà eléso, tí ọgbà eléso yóo sì fi di igbó. A óo máa ṣe ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ní gbogbo ilẹ̀ náà, ìwà òdodo yóo sì wà níbi gbogbo. Àyọrísí òdodo yóo sì jẹ́ alaafia, ìgbẹ̀yìn rẹ̀ yóo sì jẹ́ ìbàlẹ̀ àyà wa, ati igbẹkẹle OLUWA títí lae. Àwọn eniyan mi yóo máa gbé pẹlu alaafia, ní ibùgbé tí ó ní ààbò ati ibi ìsinmi tí ó ní ìbàlẹ̀ àyà. Yìnyín yóo bọ́, yóo bo gbogbo ilẹ̀, a óo sì pa ìlú náà run patapata. Ayọ̀ ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fúnrúgbìn sí etí odò yóo pọ̀, ẹ̀yin tí ẹ ní mààlúù ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ń jẹ káàkiri. O gbé! Ìwọ tí ń panirun, tí ẹnìkan kò parun, ìwọ tí ò ń hùwà ọ̀dàlẹ̀ nígbà tí ẹnìkan kò dà ọ́. Ìgbà tí o bá dáwọ́ ìpanirun dúró, nígbà náà ni a óo pa ìwọ gan-an run; nígbà tí o bá fi ìwà ọ̀dàlẹ̀ sílẹ̀, nígbà náà ni a óo dà ọ́. Ṣàánú wa OLUWA, ìwọ ni a dúró tí à ń wò. Máa ràn wá lọ́wọ́ lojoojumọ, sì máa jẹ́ olùgbàlà wa nígbà ìṣòro. Àwọn orílẹ̀-èdè sá nígbà tí wọ́n gbọ́ ariwo tí ó dàbí ti ààrá, wọ́n fọ́n ká nígbà tí o gbéra nílẹ̀. A kó ìkógun jọ bí ìgbà tí tata bo oko, àwọn eniyan dà bo ìṣúra, bí ìgbà tí eṣú bo oko. A gbé OLUWA ga! Nítorí pé ibi gíga ni ó ń gbé; yóo mú kí ìdájọ́ òtítọ́ ati òdodo kún Sioni. Yóo mú kí ìdúróṣinṣin wà ní gbogbo àkókò rẹ̀. Yóo fún ọ ní ọpọlọpọ ìgbàlà, ati ọgbọ́n, ati ìmọ̀, ìbẹ̀rù OLUWA ni ìṣúra rẹ̀. Ẹ wò ó, àwọn alágbára ń kígbe lóde, àwọn òjíṣẹ́ alaafia ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn. Òpópó ọ̀nà ṣófo, àwọn èrò kò rìn mọ́; wọ́n ń ba majẹmu jẹ́, wọn kò bìkítà fún ẹlẹ́rìí mọ́; wọ́n kò sì ka eniyan sí. Ilẹ̀ ṣófo ó sì gbẹ, ìtìjú bá òkè Lẹbanoni, gbogbo ewéko orí rẹ̀ sì rẹ̀ dànù. Ṣaroni dàbí aṣálẹ̀, igi igbó Baṣani ati ti òkè Kamẹli sì wọ́wé. OLUWA ní: “Ó yá tí n óo dìde, ó yá mi wàyí, n óo gbéra nílẹ̀. Àsìkò tó tí a óo gbé mi ga. Èrò yín dàbí fùlùfúlù, gbogbo ìṣe yín dàbí pòpórò ọkà. Èémí mi yóo jó yín run bí iná. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo dàbí ìgbà tí a sun wọ́n, tí wọ́n di eérú, àní bí igi ẹ̀gún tí a gé lulẹ̀, tí a sì dáná sun. Ẹ̀yin tí ẹ wà lókè réré, ẹ gbọ́ ohun tí mo ṣe; ẹ̀yin tí ẹ wà nítòsí, ẹ kíyèsí agbára mi.” Ẹ̀rù ń ba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ó wà ní Sioni; ìjayà mú àwọn ẹni tí kò mọ Ọlọrun. Ta ni ninu wa ló lè gbé inú iná ajónirun? Ta ni ninu wa ló lè gbé inú iná àjóòkú? Ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ bá tọ́, tí ó sì ń sọ ọ̀rọ̀ òtítọ́, ẹni tí ó kórìíra èrè àjẹjù, tí ó kọ̀, tí kò gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, tí ó di etí sí ọ̀rọ̀ àwọn tí ń gbèrò ati paniyan, tí ó sì di ojú rẹ̀ kí ó má baà rí nǹkan ibi. Ibi ààbò ni yóo máa gbé, àpáta ńlá ni yóo jẹ́ ibi ààbò rẹ̀. Yóo máa rí oúnjẹ jẹ déédé, yóo sì máa rí omi mu lásìkò, lásìkò. Ojú yín yóo rí ọba ninu ọlá ńlá rẹ̀; ẹ óo fojú yín rí ilẹ̀ tí ó lọ salalu. Ẹ óo máa ronú ìnira tí ẹ ti ní pé: “Níbo ni akọ̀wé wà? Níbo ni ẹni tí ń gba owó orí wà? Níbo sì ni ẹni tí ń ka ilé ìṣọ́ wà?” Ẹ kò ní rí àwọn aláfojúdi náà mọ́, àwọn tí wọn ń fọ èdè tí kò ní ìtumọ̀ si yín, tí wọn ń kólòlò ní èdè tí ẹ kò gbọ́. Ẹ wo Sioni, ìlú tí a yà sọ́tọ̀ fún àjọ̀dún. Ẹ óo fi ojú rí Jerusalẹmu, ibùgbé alaafia, tí àgọ́ rẹ̀ kò ní ṣídìí, tí èèkàn tí a fi kàn án mọ́lẹ̀ kò ní hú laelae, bẹ́ẹ̀ ni okùn tí a fi so ó mọ́lẹ̀ kò ní já. Ṣugbọn níbẹ̀ ni OLUWA, ninu ògo rẹ̀, yóo jẹ́ odò ńlá ati odò tí ń ṣàn fún wa; níbi tí ọkọ̀ ọlọ́pọ́n kò lè dé, ọkọ̀ ojú omi kò sì ní lè kọjá níbẹ̀. Nítorí pé OLUWA ni onídàájọ́ wa, òun ni alákòóso wa; OLUWA ni ọba wa, òun ni yóo gbà wá là. Okùn òpó-ọkọ̀ rẹ̀ ti tú, kò lè mú òpó-ọkọ̀ náà dáradára ní ipò rẹ̀ mọ́; kò sì lè gbé ìgbòkun dúró. A óo pín ọpọlọpọ ìkógun nígbà náà, kódà, àwọn arọ pàápàá yóo pín ninu rẹ̀. Kò sí ará ìlú kan tí yóo sọ pé, “Ara mi kò yá.” A óo dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tí ń gbé ibẹ̀ jì wọ́n. Ẹ súnmọ́ ibí, kí ẹ wá gbọ́, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, ẹ tẹ́tí sílẹ̀, gbogbo ẹ̀yin eniyan. Kí ilẹ̀ gbọ́ ati gbogbo ohun tí ó wà lórí rẹ̀, kí ayé tẹ́tí sílẹ̀ pẹlu gbogbo nǹkan tí ń ti inú rẹ̀ jáde. Nítorí OLUWA ń bínú sí gbogbo orílẹ̀-èdè, inú rẹ̀ sì ń ru sí àwọn eniyan ibẹ̀. Ó ti fi wọ́n sílẹ̀ fún ìparun, ó sì ti fà wọ́n kalẹ̀ fún pípa. A óo wọ́ òkú wọn jùnù, òkú wọn yóo máa rùn; ẹ̀jẹ̀ wọn yóo sì máa ṣàn lórí àwọn òkè. Oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀ yóo gbọ̀n dànù a óo ká awọsanma bí ẹni ká ìwé. Oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀ yóo jábọ́ bí ewé tií rẹ̀ sílẹ̀ lára ìtàkùn àjàrà, àní, bí ewé tií wọ́ dànù lórí igi ọ̀pọ̀tọ́. Nítorí mo ti rẹkẹ idà mi lókè ọ̀run, yóo sọ̀kalẹ̀ láti ṣe ìdájọ́ àwọn ará Edomu; yóo sọ̀kalẹ̀ sórí àwọn tí mo fẹ́ parun. OLUWA ní idà kan tí a tì bọ inú ẹ̀jẹ̀, a rì í sinu ọ̀rá, pẹlu ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ aguntan ati ti ewúrẹ́, ati ọ̀rá ara kíndìnrín àgbò. Nítorí pé OLUWA yóo rú ẹbọ ní Bosira, yóo sì pa ọpọlọpọ eniyan ní ilẹ̀ Edomu. Àwọn mààlúù igbó yóo kú pẹlu wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù ati àwọn akọ mààlúù ńlá. Ilẹ̀ wọn yóo kún fún ẹ̀jẹ̀, ọ̀rá eniyan yóo sì mú kí ilẹ̀ wọn lẹ́tù lójú. Nítorí OLUWA ti ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ fún ẹ̀san, ó ti ya ọdún kan sọ́tọ̀ tí yóo gbèjà Sioni. Àwọn odò ilẹ̀ Edomu yóo di ọ̀dà, erùpẹ̀ rẹ̀ yóo di imí ọjọ́; ilẹ̀ Edomu yóo di ọ̀dà tí ń jó bùlàbùlà. Yóo máa jó tọ̀sán-tòru, kò ní kú, yóo máa rú èéfín sókè títí lae. Yóo di aṣálẹ̀ láti ìrandíran, ẹnikẹ́ni kò ní gbabẹ̀ kọjá mọ́ títí lae. Àṣá ati òòrẹ̀ ni yóo fi ibẹ̀ ṣe ilé, òwìwí ati ẹyẹ kannakánná ni yóo máa gbé ibẹ̀. OLUWA yóo ta okùn ìdàrúdàpọ̀ lé e lórí, yóo sì na ọ̀pá ìdàrúdàpọ̀ lé àwọn ìjòyè rẹ̀ lórí. “Kò sí Ilẹ̀ Ọba Mọ́” ni a óo máa pè é. Gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ yóo parẹ́. Ẹ̀gún yóo hù ninu ààfin rẹ̀, ẹ̀gún òṣùṣú ati ẹ̀gún ọ̀gàn yóo hù ninu àwọn ìlú olódi rẹ̀. Wọn yóo di ibùgbé fún àwọn ọ̀fàfà ati ẹyẹ ògòǹgò, àwọn ẹranko ìgbẹ́ ati ìkookò yóo jọ máa gbé ibẹ̀, àwọn ewúrẹ́ igbó yóo máa ké pe ara wọn. Iwin yóo rí ibi máa gbé, yóo sì rí ààyè máa sinmi níbẹ̀. Òwìwí yóo pa ìtẹ́ sibẹ, tí yóo máa yé sí. Yóo pamọ, yóo ràdọ̀ bo àwọn ọmọ rẹ̀, yóo sì máa tọ́jú wọn níbẹ̀. Àwọn àṣá yóo péjọ sibẹ, olukuluku wọn, pẹlu ekeji rẹ̀. Ẹ lọ wá inú ìwé OLUWA, kí ẹ ka ohun tí ó wà níbẹ̀. Kò sí ọ̀kan ninu àwọn wọnyi tí kò ní sí níbẹ̀, kò sí èyí tí kò ní ní ẹnìkejì. Nítorí OLUWA ni ó pàṣẹ bẹ́ẹ̀, ẹ̀mí rẹ̀ ni ó sì kó wọn jọ. Ó ti ṣẹ́ gègé fún wọn, ó ti fi okùn wọ̀n ọ́n kalẹ̀ fún wọn. Àwọn ni wọn óo ni ín títí lae, wọn óo sì máa gbé ibẹ̀ láti ìrandíran. Inú aṣálẹ̀ ati ilẹ̀ gbígbẹ yóo dùn, aṣálẹ̀ yóo yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, yóo rúwé, yóo sì tanná. Nítòótọ́ yóo tanná bí òdòdó, yóo yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, yóo sì kọrin. Ògo Lẹbanoni yóo di tìrẹ ati iyì Kamẹli ati ti Ṣaroni. Wọn óo rí ògo OLUWA, wọn óo rí ọlá ńlá Ọlọrun wa. Ẹ gbé ọwọ́ tí kò lágbára ró. Ẹ fún orúnkún tí kò lágbára ní okun. Ẹ sọ fún àwọn tí àyà wọn ń já pé: “Ẹ ṣe ara gírí, ẹ má bẹ̀rù. Ẹ wò ó! Ọlọrun yín óo wá pẹlu ẹ̀san, ó ń bọ̀ wá gbẹ̀san gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun; ó ń bọ̀ wá gbà yín là.” Ojú afọ́jú yóo là nígbà náà, etí adití yóo sì ṣí; arọ yóo máa fò bí ìgalà, odi yóo sì máa kọ orin ayọ̀. Nítorí odò ńlá yóo ṣàn jáde ninu aginjù àwọn odò kéékèèké yóo máa ṣàn ninu aṣálẹ̀. Ilẹ̀ iyanrìn gbígbóná yóo di adágún omi ilẹ̀ gbígbẹ yóo di orísun omi, ibi tí ọ̀fàfà fi ṣe ilé tẹ́lẹ̀ yóo di àbàtà, èèsún ati ìyè yóo máa dàgbà níbẹ̀. Òpópónà kan yóo wà níbẹ̀, a óo máa pè é ní Ọ̀nà Ìwà Mímọ́; nǹkan aláìmọ́ kan kò ní gba ibẹ̀ kọjá, àwọn aláìgbọ́n kò sì ní dẹ́ṣẹ̀ níbẹ̀. Kò ní sí kinniun níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹranko burúkú kankan kò ní gba ibẹ̀. A kò ní rí wọn níbẹ̀, àwọn tí a ti rà pada ni yóo gba ibẹ̀. Àwọn tí OLUWA rà pada yóo pada, wọn óo wá sí Sioni pẹlu orin, ayọ̀ ayérayé yóo kún inú wọn. Wọn óo rí ayọ̀ ati ìdùnnú gbà ìbànújẹ́ ati òṣé yóo sá kúrò níbẹ̀. Ní ọdún kẹrinla tí Ọba Hesekaya jọba, Senakeribu, ọba Asiria gbógun ti gbogbo ìlú olódi Juda, ó sì kó wọn. Ọba Asiria rán Rabuṣake (olórí ogun rẹ̀), pẹlu ọpọlọpọ ọmọ ogun; láti Lakiṣi sí ọba Hesekaya ní Jerusalẹmu. Nígbà tí wọn dé ibi tí omi tí ń ṣàn wọ ìlú láti orí òkè tí ó wà ní ọ̀nà pápá alágbàfọ̀, wọ́n dúró níbẹ̀. Eliakimu, ọmọ Hilikaya tí ó jẹ́ alákòóso ààfin jáde lọ bá wọn pẹlu Ṣebina, akọ̀wé ilé ẹjọ́, ati Joa ọmọ Asafu, akọ̀wé ààfin. Rabuṣake bá sọ fún wọn pé, “Ẹ sọ fún Hesekaya pé ọba ńlá Asiria ní kí ló gbójú lé rí? Ó ní ṣé Hesekaya rò pé ọ̀rọ̀ ẹnu ni ọgbọ́n ati agbára tí wọ́n fi ń jagun ni; àbí ta ló gbójú lé tí ó fi ń ṣàìgbọràn sí òun? Ó ní Ijipti tí Hesekaya gbára lé dàbí kí eniyan fi ìyè ṣe ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀, ìyè tí yóo dá, tí yóo sì gún ẹnikẹ́ni tí ó bá gbára lé e lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ ni Farao ọba Ijipti jẹ́ sí gbogbo àwọn tí ó bá gbára lé e. “Ó ní bí Hesekaya bá sì sọ fún òun pé, OLUWA Ọlọrun àwọn ni àwọn gbójú lé, òun óo bi í pé, ṣé kì í ṣe ojúbọ OLUWA náà ati àwọn pẹpẹ ìrúbọ rẹ̀ ni Hesekaya wó lulẹ̀ nígbà tí ó sọ fún àwọn ará Juda ati àwọn ará Jerusalẹmu pé, ẹyọ pẹpẹ kan ni kí wọ́n ti máa sin OLUWA?” Rabuṣake ní, “Mo fẹ́ kí Hesekaya bá oluwa mi, ọba Asiria, ṣe pàṣípààrọ̀ kan, n óo fún un ní ẹgbaa ẹṣin bí ó bá lè rí eniyan tó tí ó lè gùn wọ́n. Báwo ni ó ṣe lè lé ẹni tí ó kéré jù ninu àwọn olórí-ogun oluwa mi pada sẹ́yìn, nígbà tí ó jẹ́ pé Ijipti ni ó gbójú lé pé wọn óo fún un ní kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin? Ẹ bi í pé, ṣé kò mọ̀ pé wíwá tí mo wá láti gbógun ti ìlú yìí ati láti pa á run kò ṣẹ̀yìn OLUWA? OLUWA ni ó sọ fún mi pé kí n lọ gbógun ti ilẹ̀ yìí, kí n sì pa á run.” Nígbà náà ni Eliakimu ati Ṣebina ati Joa sọ fún Rabuṣake pé, “Jọ̀wọ́, èdè Aramaiki ni kí o fi bá wa sọ̀rọ̀, nítorí pé àwa náà gbọ́ Aramaiki. Má fi èdè Juda bá wa sọ̀rọ̀ kí àwọn ará wa tí ó wà lórí odi má baà gbọ́.” Ṣugbọn Rabuṣake dá wọn lóhùn pé, “Ṣé ẹ rò pé ẹ̀yin ati oluwa yín nìkan ni oluwa mi rán mi pé kí n jíṣẹ́ yìí fún ni? Ṣé kò yẹ kí gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n jókòó lórí odi ìlú yìí fetí wọn gbọ́ pé, ati àwọn ati ẹ̀yin, ẹ ti gbé, ẹ o máa jẹ ìgbọ̀nsẹ̀ ara yín, ẹ óo sì máa mu ìtọ̀ yín?” Rabuṣake bá dìde dúró, ó sì kígbe ní èdè Juda, ó ní, “Ẹ gbọ́ ohun tí ọba ńlá, ọba Asiria wí: Ọba ní kí ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekaya tàn yín jẹ, nítorí kò ní le gbà yín là. Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekaya mú kí ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, kí ó máa wí fún yín pé, ‘Dájúdájú OLUWA yóo gbà wá, ọba Asiria kò ní fi ogun kó ìlú yìí.’ “Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ Hesekaya; nítorí ọba Asiria ní kí ẹ bá òun ṣe àdéhùn alaafia kí ẹ jáde tọ òun wá. Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, olukuluku yín ni yóo máa jẹ èso àjàrà ati èso ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, olukuluku yín yóo sì máa mu omi ninu kànga rẹ̀; títí òun óo fi wá mú yín lọ sí ilẹ̀ mìíràn tí ó dàbí ilẹ̀ yín, ilẹ̀ tí ó kún fún ọkà ati ọtí, tí oúnjẹ ati ọgbà àjàrà ti pọ̀. Ẹ ṣọ́ra kí Hesekaya má baà fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣì yín lọ́nà, kí ó máa sọ pé, ‘OLUWA yóo gbà wá.’ Ṣé ọ̀kankan ninu àwọn oriṣa àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ti gba ilẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ Ọba Asiria rí? Àwọn oriṣa Hamati ati Aripadi dà? Níbo ni àwọn oriṣa Sefafaimu wà? Ṣé wọn gba àwọn ará Samaria kalẹ̀ lọ́wọ́ mi? Èwo ninu àwọn oriṣa ilẹ̀ wọnyi ni ó gba ilẹ̀ rẹ̀ kalẹ̀ lọ́wọ́ mi, tí ẹ fi rò pé OLUWA yóo gba Jerusalẹmu kalẹ̀ lọ́wọ́ mi?” Gbogbo wọn dákẹ́, kò sí ẹnìkan tí ó sọ nǹkankan nítorí ọba ti pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ dá a lóhùn. Eliakimu, ọmọ Hilikaya tí ó jẹ́ alákòóso ààfin ati Ṣebina, akọ̀wé ilé ẹjọ́, ati Joa, ọmọ Asafu, akọ̀wé ààfin wá sọ́dọ̀ Hesekaya pẹlu àwọn ti aṣọ wọn tí wọ́n ti fàya láti fi ìbànújẹ́ wọn hàn, wọ́n sì sọ ohun tí Rabuṣake wí fún un. Nígbà tí Hesekaya ọba gbọ́, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora, ó sì wọ inú ilé OLUWA lọ. Ó rán Eliakimu tí ń ṣàkóso ààfin, ati Ṣebina akọ̀wé ilé ẹjọ́ ati àwọn àgbààgbà alufaa, wọ́n da aṣọ ọ̀fọ̀ bora, wọ́n lọ sọ́dọ̀ wolii Aisaya, ọmọ Amosi. Wọ́n jíṣẹ́ fún un, wọ́n ní, “Hesekaya ní kí á sọ fún ọ pé: ‘Ọjọ́ ìṣòro ni ọjọ́ òní, ọjọ́ ìyà, ati ọjọ́ ẹ̀sín. Ọmọ ń mú aboyún, ó dé orí ìkúnlẹ̀, ṣugbọn kò sí agbára láti bíi. Ó ṣeéṣe kí OLUWA Ọlọrun rẹ ti gbọ́ iṣẹ́ tí ọba Asiria rán Rabuṣake, iranṣẹ rẹ̀, pé kí ó wá fi Ọlọrun alààyè ṣe ẹlẹ́yà, kí OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe ìdájọ́ tí ó tọ́ lórí irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀! Nítorí náà gbé ohùn ẹ̀bẹ̀ sókè kí o gbadura fún àwọn eniyan tí ó kù.’ ” Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ Hesekaya ọba jíṣẹ́ fún Aisaya, Aisaya dá wọn lóhùn pé, “Ẹ wí fún oluwa yín pé OLUWA ní: ‘Má bẹ̀rù nítorí ọ̀rọ̀ tí o gbọ́ tí iranṣẹ ọba Asiria sọ tí ó ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà. Ìwọ máa wò ó, n óo fi ẹ̀mí kan sí inú rẹ̀, yóo gbọ́ ìròyìn èké kan, yóo sì pada lọ sí ilẹ̀ rẹ̀. Nígbà tí ó bá dé ilé n óo jẹ́ kí wọ́n fi idà pa á.’ ” Rabuṣake gbọ́ pé ọba Asiria ti kúrò ní Lakiṣi, nítorí náà, ó lọ bá a níbi tí ó ti ń bá àwọn ará Libina jagun. Ibẹ̀ ni àwọn kan ti ròyìn fún ọba Asiria pé, Tirihaka ọba Etiopia ń bọ̀ wá gbógun tì í. Nígbà tí ó gbọ́, ó rán ikọ̀ lọ bá Hesekaya, ó ní: “Ẹ sọ fún Hesekaya ọba Juda pé kí ó má jẹ́ kí Ọlọrun rẹ̀ tí ó gbójú lé ṣì í lọ́nà kí ó sọ pé ọba Asiria kò ní fi ogun kó Jerusalẹmu. Ṣebí Hesekaya ti gbọ́ ohun tí àwọn ọba Asiria ṣe sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, tí wọ́n pa wọ́n run patapata. Ṣé Hesekaya rò pé a óo gba òun là ni? Ṣé àwọn oriṣa orílẹ̀-èdè tí àwọn baba ńlá mi parun gbà wọ́n sílẹ̀, àwọn orílẹ̀-èdè bíi Gosani ati Harani, Resefu ati àwọn ará Edẹni tí ń gbé Telasari? Ọba Hamati dà? Ọba Aripadi ńkọ́? Níbo ni ọba ìlú Sefafaimu ati ọba Hena ati ọba Ifa wà?” Hesekaya gba ìwé náà lọ́wọ́ àwọn ikọ̀ ọba Asiria, ó kà á. Nígbà tí ó kà á tán, ó gbéra, ó lọ sí ilé OLUWA, ó bá tẹ́ ìwé náà sílẹ̀ níwájú OLUWA, Hesekaya bá gbadura sí OLUWA, ó ní: “Ìwọ OLUWA àwọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israẹli, ìwọ tí ìtẹ́ rẹ wà lórí àwọn Kerubu, ìwọ nìkan ni Ọlọrun gbogbo ìjọba ayé, ìwọ ni ó sì dá ọ̀run ati ayé. Dẹtí sílẹ̀ OLUWA, kí o gbọ́. La ojú rẹ, OLUWA, kí o máa wo nǹkan. Gbọ́ irú iṣẹ́ tí Senakeribu rán tí ó ń fi ìwọ Ọlọrun alààyè ṣe ẹlẹ́yà. Lóòótọ́ ni, OLUWA, pé àwọn ọba Asiria ti pa gbogbo orílẹ̀-èdè run tàwọn ti ilẹ̀ wọn, ati pé wọ́n ju oriṣa wọn sinu iná, nítorí pé wọn kì í ṣe Ọlọrun. Iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni wọ́n, tí wọ́n fi igi ati òkúta ṣe, nítorí náà ni wọ́n ṣe lè pa wọ́n run. Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun wa, gbà wá lọ́wọ́ rẹ̀, kí gbogbo ìjọba ayé lè mọ̀ pé ìwọ nìkan ni OLUWA.” Aisaya ọmọ Amosi bá ranṣẹ sí Hesekaya, pé OLUWA, Ọlọrun Israẹli ní, nítorí pé Hesekaya ti gbadura sí òun nípa Senakeribu ọba Asiria, ohun tí OLUWA sọ nípa rẹ̀ ni pé: “Sioni bu ẹnu àtẹ́ lù ọ́, Senakeribu, ó fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà, Jerusalẹmu ń yọ ṣùtì sí ọ. Ta ni ò ń sọ̀rọ̀ aṣa sí, tí ò ń fí ń ṣe ẹlẹ́yà? Ta ni ò ń ṣíjú wò pẹlu ìgbéraga? Ṣé Ẹni Mímọ́ Israẹli ni o ṣe irú èyí sí? O rán àwọn iranṣẹ rẹ láti fi OLUWA ṣe ẹlẹ́yà, o ní, ‘Mo ti fi ọpọlọpọ kẹ̀kẹ́ ogun mi gun orí àwọn òkè gíga lọ, mo dé góńgó orí òkè Lẹbanoni. Mo ti gé àwọn igi kedari rẹ̀ tí ó ga jùlọ lulẹ̀, ati àwọn ààyò igi firi rẹ̀. Mo ti dé ibi tí ó ga jùlọ ní ilẹ̀ rẹ̀, ati igbó rẹ̀ tí ó dí jùlọ. Mo gbẹ́ kànga mo sì mu omi ninu wọn. Mo ti fi ẹsẹ̀ mi tẹ gbogbo omi odò kéékèèké ilẹ̀ Ijipti ní àtẹ̀gbẹ.’ “Ṣé o kò tíì gbọ́ pé láti ìgbà pípẹ́, ni mo ti pinnu ohun tí mò ń mú ṣẹ nisinsinyii? Láti ayébáyé ni mo ti ṣètò rẹ̀, pé kí o wó ìlú olódi palẹ̀, kí ó di òkítì àlàpà. Kí àwọn eniyan tí ń gbé inú wọn má ní agbára mọ́, kí wọ́n wà ninu ìdààmú ati ìpayà. Kí wọ́n dàbí ewé inú oko ati bíi koríko tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ hù bí koríko tí ó hù lórí òrùlé, tíí gbẹ kí ó tó dàgbà. “Mo mọ ìjókòó rẹ. Mo mọ ìjáde ati ìwọlé rẹ, ati inú tí ò ń bá mi bí. Nítorí pé ò ń bá mi bínú, mo sì ti gbọ́ nípa ìwà ìgbéraga rẹ, n óo sì fi ìwọ̀ kọ́ ọ ní imú, n óo fi ìjánu bọ̀ ọ́ ni ẹnu, n óo sì dá ọ pada sí ọ̀nà tí o gbà wá. “Ohun tí yóo jẹ́ àmì fún ọ nìyí Hesekaya: Ní ọdún yìí, ohun tí ó bá lalẹ̀ hù ni ẹ óo máa jẹ. Ní ọdún tí ń bọ̀ pẹlu, ohun tí ó bá lalẹ̀ hù ni ẹ óo máa jẹ bákan náà. Ní ọdún kẹta, ẹ gbin nǹkan ọ̀gbìn, kí ẹ sì kórè rẹ̀, ẹ ṣe ọgbà àjàrà kí ẹ sì máa jẹ èso inú rẹ̀. Àwọn ọmọ Juda tí ó bá ṣẹ́kù yóo fi gbòǹgbò múlẹ̀, wọn óo sì so èso. Àwọn eniyan yóo ṣẹ́kù tí yóo wá láti Jerusalẹmu àwọn tí wọn yóo sá àsálà yóo wá láti orí òkè Sioni. Ìtara OLUWA àwọn ọmọ ogun ni yóo ṣe èyí. “Nítorí náà, ohun tí OLUWA wí nípa ọba Asiria ni pé, ‘Kò ní wọ inú ìlú yìí, kò sì ní ta ọfà sí i. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kò ní kó apata wọ inú rẹ̀. Wọn kò sì ní dó tì í. Ọ̀nà tí ọba Asiria gbà wá ni yóo gbà pada lọ, kò ní fi ẹsẹ̀ kan inú ìlú yìí. N óo dáàbò bo ìlú yìí, n óo sì gbà á sílẹ̀ nítorí tèmi ati nítorí Dafidi iranṣẹ mi.’ ” Angẹli OLUWA bá lọ sí ibùdó àwọn ọmọ ogun Asiria, ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹsan-an ó lé ẹgbẹẹdọgbọn (185,000) ninu wọn. Nígbà tí wọn jí ní àfẹ̀mọ́júmọ́ òkú kún ilẹ̀ lọ kítikìti. Senakeribu ọba Asiria bá pada sílé, ó ń lọ gbé ìlú Ninefe. Ní ọjọ́ kan, ó lọ bọ Nisiroku, oriṣa rẹ̀, àwọn meji ninu àwọn ọmọ rẹ̀: Adirameleki ati Ṣareseri, sì fi idà gún un pa, wọ́n bá sá lọ sí ilẹ̀ Ararati. Esaradoni ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀. Ní àkókò náà, Hesekaya ṣàìsàn, àìsàn náà pọ̀; ó fẹ́rẹ̀ kú. Aisaya wolii, ọmọ Amosi tọ̀ ọ́ wá ní ọjọ́ kan, ó wí fún un pé: “OLUWA ní kí n sọ fún ọ pé kí o ṣe ètò ilé rẹ, nítorí pé o óo kú ni, o kò ní yè.” Hesekaya bá kọjú sí ògiri, ó gbadura sí OLUWA, ó ní, “OLUWA, dákun, mo bẹ̀ ọ́ ni, ranti bí mo ti ṣe fi tọkàntọkàn rìn níwájú rẹ pẹlu òtítọ́ inú, tí mo sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú rẹ.” Hesekaya bá sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn. OLUWA bá sọ fún Aisaya pé kí ó lọ sọ fún Hesekaya pé, òun, OLUWA Ọlọrun Dafidi baba ńlá rẹ̀ ti gbọ́ adura rẹ̀. Oun ti rí omijé rẹ̀, òun óo sì fi ọdún mẹẹdogun kún ọjọ́ ayé rẹ̀. OLUWA ní òun óo gba Hesekaya lọ́wọ́ ọba Asiria, òun óo gbèjà ìlú Jerusalẹmu, òun óo sì dáàbò bò ó. *** *** *** *** *** *** *** *** *** *** *** *** *** *** Aisaya bá sọ fún Hesekaya pé kí wọn bá a wá èso ọ̀pọ̀tọ́ kí wọn lọ̀ ọ́, kí wọn fi lé ojú oówo tí ó mú un, kí ó lè gbádùn. Hesekaya bá bèèrè pé, kí ni àmì tí òun óo fi mọ̀ pé òun óo tún fi ẹsẹ̀ òun tẹ ilé Olúwa? Aisaya ní, àmì tí OLUWA fún Hesekaya tí yóo mú kí ó dá a lójú pé òun OLUWA yóo ṣe ohun tí òun ṣèlérí nìyí: Òun óo mú kí òjìji oòrùn ìrọ̀lẹ́ pada sẹ́yìn ní àtẹ̀gùn mẹ́wàá lórí àtẹ̀gùn Ahasi. Oòrùn bá yí pada nítòótọ́, òjìji sì pada sẹ́yìn ní àtẹ̀gùn mẹ́wàá tí ó ti sọ tẹ́lẹ̀. Orin Ọpẹ́ tí Hesekaya kọ Orin tí Hesekaya ọba Juda kọ sílẹ̀ nígbà tí ó ṣàìsàn tí Ọlọrun sì wò ó sàn nìyí: Mo ti rò pé n óo kú lọ́jọ́ àìpé, ati pé a óo sé mi mọ́ inú ibojì, níbẹ̀ ni n óo sì ti lo ìyókù ọjọ́ ayé mi. Mo rò pé n kò ní tún fojú kan OLUWA mọ́ ní ilẹ̀ alààyè, ati pé n kò ní sí láàyè mọ́ láti tún fi ojú mi kan ẹnikẹ́ni. A tú àgọ́ mi palẹ̀ bí àgọ́ darandaran, a sì ká a lọ kúrò lọ́dọ̀ mi. Mo ká ayé mi bí aṣọ tí wọn ń hun. Ó sì gé mi kúrò bí aṣọ tí wọ́n gé kúrò lórí òfì. Mo ti kọ́ rò pé tọ̀sán-tòru ni ìwọ OLUWA ń fi òpin sí ayé mi. Mo kígbe fún ìrànlọ́wọ́ títí ilẹ̀ fi mọ́ ó fọ́ gbogbo egungun mi bí kinniun ti máa ń fọ́ egungun. Tọ̀sán-tòru mo rò pé Ọlọrun ń fi òpin sí ayé mi ni. Ọkàn mi ń ṣe hílàhílo bí ẹyẹ aláàpáǹdẹ̀dẹ̀ ati ẹyẹ àkọ̀, mò ń ké igbe arò bí àdàbà. Mo wòkè títí ojú ń ro mí, ara ń ní mí, OLUWA, nítorí náà ṣe ààbò mi. Ṣugbọn kí ni mo lè sọ? Nítorí pé ó ti bá mi sọ̀rọ̀, òun fúnrarẹ̀ ni ó sì ṣe é Oorun kò kùn mí nítorí pé ọkàn mi bàjẹ́. OLUWA, nǹkan wọnyi ni ó mú eniyan wà láàyè, ninu gbogbo rẹ̀ èmi náà yóo wà láàyè. Áà, jọ̀wọ́ wò mí sàn, kí o mú mi wà láàyè. Nítorí ìlera mi ni mo ṣe ní ìbànújẹ́ lọpọlọpọ; ìwọ ni o dì mí mú, tí n kò fi jìn sinu kòtò ìparun, nítorí o ti sọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi di ohun ìgbàgbé. Ibojì kò lè dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ikú kò lè yìn ọ́; kò sí ìrètí mọ́ fún àwọn tí wọ́n ti lọ sinu isà òkú, wọn kò lè gbẹ́kẹ̀lé òdodo rẹ mọ́. Alààyè, àní alààyè, ni ó lè máa yìn ọ́ bí mo ti yìn ọ́ lónìí. Baba a máa kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, nípa òdodo rẹ. OLUWA yóo gbà mí là, a óo fi àwọn ohun èlò orin olókùn kọrin ninu ilé OLUWA, ní gbogbo ọjọ́ ayé wa. Ní àkókò náà Merodaki Baladani ọmọ Baladani, ọba Babiloni, fi ìwé ati ẹ̀bùn rán àwọn ikọ̀ kan sí Hesekaya, nítorí ó gbọ́ pé ara rẹ̀ kò ti dá tẹ́lẹ̀ ṣugbọn ara rẹ̀ ti wá le. Hesekaya gbà wọ́n lálejò, ó sì fi àwọn nǹkan tí ó wà ninu ilé ìṣúra rẹ̀ hàn wọ́n, fadaka ati wúrà, àwọn nǹkan olóòórùn dídùn ati òróró olówó iyebíye, ilé ìkó nǹkan ìjà ogun sí, ati gbogbo nǹkan tí ó wà ninu ilé ìṣúra. Kò sí nǹkan tí ó wà ní ìpamọ́ ní ààfin Hesekaya ní ilé rẹ̀ tí kò fihàn wọ́n. Lẹ́yìn náà Aisaya wolii tọ Hesekaya ọba lọ, ó bi í pé, “Kí ni àwọn ọkunrin wọnyi wí, láti ibo ni wọ́n sì ti wá sọ́dọ̀ rẹ?” Hesekaya dáhùn, ó ní, “Láti ilẹ̀ òkèèrè, ní Babiloni ni wọ́n ti wá.” Aisaya tún bi í pé, “Kí ni wọ́n rí láàfin rẹ?” Hesekaya dáhùn, ó ní, “Gbogbo ohun tó wà láàfin ni wọ́n rí. Kò sí ohun tí ó wà ní ilé ìṣúra mi tí n kò fihàn wọ́n.” Aisaya bá sọ fún Hesekaya, pé, “Gbọ́ ohun tí OLUWA àwọn ọmọ ogun wí: Ó ní, ‘Ọjọ́ ń bọ̀ tí a óo ru gbogbo ohun tí ó wà láàfin rẹ lọ sí Babiloni, ati gbogbo ìṣúra tí àwọn baba ńlá rẹ ti kó jọ títí di òní. Kò ní ku nǹkankan.’ OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. ‘A óo kó ninu àwọn ọmọ bíbí inú rẹ lọ, a óo sì fi wọ́n ṣe ìwẹ̀fà láàfin ọba Babiloni.’ ” Hesekaya dá Aisaya lóhùn, ó ní, “Ohun rere ni OLUWA sọ.” Ó sọ bẹ́ẹ̀ nítorí ó rò pé alaafia ati ìfọ̀kànbalẹ̀ yóo wà ní àkókò tòun. Ọlọrun yín ní, “Ẹ tù wọ́n ninu, ẹ tu àwọn eniyan mi ninu. Ẹ bá Jerusalẹmu sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ẹ ké sí i pé, ogun jíjà rẹ̀ ti parí, a ti dárí àìṣedéédé rẹ̀ jì í. OLUWA ti jẹ ẹ́ níyà ní ìlọ́po meji nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.” Ẹ gbọ́ ohùn akéde kan tí ń wí pé, “Ẹ tún ọ̀nà OLUWA ṣe ninu aginjù, ẹ la òpópónà títọ́ fún Ọlọrun wa ninu aṣálẹ̀. Gbogbo àfonífojì ni a óo ru sókè, a óo sì sọ àwọn òkè ńlá ati òkè kéékèèké di pẹ̀tẹ́lẹ̀: Gbogbo ọ̀nà tí ó wọ́ ni yóo di títọ́, ọ̀nà gbágun-gbàgun yóo sì di títẹ́jú. Ògo OLUWA yóo farahàn, gbogbo eniyan yóo sì jọ fojú rí i. OLUWA ni ó fi ẹnu ara rẹ̀ sọ bẹ́ẹ̀.” Mo gbọ́ ohùn kan tí ń wí pé, “Kígbe!” Mo bá bèèrè pé, “Igbe kí ni kí n ké?” Ó ní, “Kígbe pé, koríko ṣá ni gbogbo eniyan, gbogbo ẹwà sì dàbí òdòdó inú pápá. Koríko a máa rọ, òdòdó a sì máa rẹ̀ nígbà tí OLUWA bá fẹ́ afẹ́fẹ́ lù ú. Dájúdájú koríko ni eniyan. Koríko a máa rọ, òdòdó a sì máa rẹ̀; ṣugbọn ọ̀rọ̀ Ọlọrun wa dúró títí lae.” Gun orí òkè gíga lọ, ìwọ Sioni, kí o máa kéde ìyìn rere. Gbé ohùn rẹ sókè pẹlu agbára Jerusalẹmu, ìwọ tí ò ń kéde ìyìn rere ké sókè má ṣe bẹ̀rù; sọ fún àwọn ìlú Juda pé, “Ẹ wo Ọlọrun yín.” Ẹ wò ó! OLUWA Ọlọrun ń bọ̀ pẹlu agbára ipá rẹ̀ ni yóo fi máa ṣe àkóso. Ẹ wò ó! Èrè rẹ̀ ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀, ẹ̀san rẹ̀ sì ń bẹ níwájú rẹ̀. Yóo bọ́ agbo ẹran bí olùṣọ́-aguntan. Yóo kó àwọn ọ̀dọ́ aguntan jọ sí apá rẹ̀, yóo gbé wọn mọ́ àyà rẹ̀. Yóo sì máa fi sùúrù da àwọn tí wọn lọ́mọ lẹ́yìn láàrin wọn. Ta ló lè fi kòtò ọwọ́ wọn omi òkun? Ta ló lè fìka wọn ojú ọ̀run, Kí ó kó erùpẹ̀ ilẹ̀ ayé sinu òṣùnwọ̀n? Ta ló lè gbé àwọn òkè ńlá ati àwọn kéékèèké sórí ìwọ̀n? Ta ló darí Ẹ̀mí OLUWA, ta ló sì tọ́ ọ sọ́nà gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn rẹ̀? Ọwọ́ ta ni OLUWA ti gba ìmọ̀ràn tí ó fi ní òye, ta ló kọ́ ọ bí wọ́n ṣe ń dájọ́ ẹ̀tọ́, tí ó kọ́ ọ ní ìmọ̀, tí ó sì fi ọ̀nà òye hàn án? Wò ó, àwọn orílẹ̀-èdè dàbí ìkán omi kan ninu garawa omi, ati bí ẹyọ eruku kan lórí òṣùnwọ̀n. Ẹ wò ó, ó mú àwọn erékùṣù lọ́wọ́ bí àtíkè. Gbogbo igi igbó Lẹbanoni kò tó fún iná ẹbọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹranko ibẹ̀ kò tó fún ẹbọ sísun. Gbogbo orílẹ̀-èdè kò tó nǹkan níwájú rẹ̀, wọn kò jámọ́ nǹkan lójú rẹ̀, òfo ni wọ́n. Ta ni ẹ lè fi Ọlọrun wé, tabi kí ni ẹ lè fi ṣe àkàwé rẹ̀? Ṣé oriṣa ni! Tí oníṣẹ́ ọwọ́ ṣe; tí alágbẹ̀dẹ wúrà yọ́ wúrà bò tí ó sì fi fadaka ṣe ẹ̀wọ̀n fún? Ẹni tí ó bá talaka, tí kò lágbára nǹkan ìrúbọ, a wá igi tí kò lè rà, tí kò sì lè ju; a wá agbẹ́gilére tí ó mọṣẹ́, láti bá a gbẹ́ ère tí kò lè paradà. Ṣé ẹ kò tíì mọ̀? Ẹ kò sì tíì gbọ́? Ṣé wọn kò sọ fun yín láti ìbẹ̀rẹ̀, kò sì ye yín láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, pé: Òun ni ó jókòó lókè àyíká ayé, àwọn eniyan inú rẹ̀ sì dàbí tata lójú rẹ̀. Òun ni ó ta awọsanma bí aṣọ títa, ó sì ta á bí àgọ́, ó ń gbébẹ̀. Ẹni tí ó sọ àwọn ọba di ẹni ilẹ̀, ó sọ àwọn olóyè ayé di asán. Wọ́n fẹ́rẹ̀ má ì tíì gbìn wọ́n, wọ́n fẹ́rẹ̀ má ì tíì ta gbòǹgbò wọlẹ̀; nígbà tí ó fẹ́ afẹ́fẹ́ lù wọ́n, tí wọ́n fi rọ bí ewéko, tí ìjì sì gbé wọn lọ bí àgékù koríko. Ta ni ẹ óo wá fi mí wé, tí n óo sì dàbí rẹ̀? Èmi Ẹni Mímọ́ ni mo bèèrè bẹ́ẹ̀. Ẹ gbójú sókè kí ẹ wo ojú ọ̀run, ta ni ó dá àwọn nǹkan tí ẹ rí wọnyi? Ẹni tí ó kó àwọn ìràwọ̀ sójú ọ̀run bí ọmọ ogun, tí ó ń pè wọ́n jáde lọ́kọ̀ọ̀kan, tí ó sì mọ olukuluku mọ́ orúkọ rẹ̀. Nítorí bí ipá rẹ̀ ti tó, ati bí agbára rẹ̀ ti pọ̀ tó, ẹyọ ọ̀kan ninu wọn kò di àwátì. Kí ló dé, Jakọbu, tí o fi ń rojọ́? Kí ló ṣe ọ́, Israẹli, tí o fi ń sọ pé, “OLUWA kò mọ ohun tí ń ṣe mí, Ọlọrun kò sì bìkítà nípa ẹ̀tọ́ mi.” Ṣé o kò tíì mọ̀, o kò sì tíì gbọ́ pé Ọlọrun ayérayé ni OLUWA, Ẹlẹ́dàá gbogbo ayé. Kì í rẹ̀ ẹ́, bẹ́ẹ̀ ni agara kì í dá a. Àwámárìídìí ni òye rẹ̀. A máa fún aláàárẹ̀ ní okun. A sì máa fún ẹni tí kò lágbára ní agbára. Yóo rẹ àwọn ọ̀dọ́ pàápàá, agara óo sì dá wọn, àwọn ọdọmọkunrin yóo tilẹ̀ ṣubú lulẹ̀ patapata. Ṣugbọn àwọn tí ó bá dúró de OLUWA yóo máa gba agbára kún agbára. Wọn óo máa fi ìyẹ́ fò lọ sókè bí ẹyẹ idì. Wọn óo máa sáré, agara kò ní dá wọn; wọn óo máa rìn, kò sì ní rẹ̀ wọ́n. “Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́, kí ẹ sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, ẹ̀yin erékùṣù, kí àwọn eniyan gba agbára kún agbára wọn, kí wọ́n súnmọ́ ìtòsí, kí wọ́n sọ tẹnu wọn, ẹ jẹ́ kí á pàdé ní ilé ẹjọ́. “Ta ló gbé ẹnìkan dìde ní ìhà ìlà oòrùn? Tí ó ń ṣẹgun ní ibikíbi tí ó bá fẹsẹ̀ tẹ̀? Ta ló fi àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́ tí ó fi lè tẹ àwọn ọba mọ́lẹ̀? Idà rẹ̀ gé wọn bí eruku, ọfà rẹ̀ sì tú wọn ká bí àgékù koríko. A máa lépa wọn, a sì máa kọjá wọn láìléwu, ní ọ̀nà tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò tẹ̀ rí. Ta ló ṣe èyí? Iṣẹ́ ọwọ́ ta sì ni? Tí ó pe ìran dé ìran láti ìbẹ̀rẹ̀? Èmi OLUWA ni, ẹni àkọ́kọ́ ati ẹni ìkẹyìn. “Àwọn erékùṣù rí i, ẹ̀rù bà wọ́n, gbogbo òpin ayé gbọ̀n rìrì wọ́n ti súnmọ́ tòsí, wọ́n ti dé. Olukuluku ń ran ẹnìkejì rẹ̀ lọ́wọ́, ó ń sọ fún arakunrin rẹ̀ pé, ‘Ṣara gírí.’ Agbẹ́gilére ń gba alágbẹ̀dẹ wúrà níyànjú ẹni tí ń fi òòlù lu irin ń kí ẹni tí ń dán irin tí wọ́n ti rọ, Ó ń wí pé: ‘Òjé tí a fi jó o dára.’ Wọ́n kàn án ní ìṣó, ó le dáradára, kò le mì. “Ìwọ ní tìrẹ, Israẹli iranṣẹ mi, Jakọbu, ìwọ tí mo ti yàn, ọmọ bíbí inú Abrahamu, ọ̀rẹ́ mi. Ìwọ tí mo mú wá láti òpin ayé, tí mo pè láti ìkangun ayé tí ó jìnnà jùlọ, mo wí fún ọ pé, ‘Iranṣẹ mi ni ọ́, mo ti yàn ọ́, n kò ní ta ọ́ nù.’ Má bẹ̀rù, nítorí mo wà pẹlu rẹ, má fòyà, nítorí èmi ni Ọlọrun rẹ. N óo fún ọ ní agbára, n óo sì ràn ọ́ lọ́wọ́; ọwọ́ ọ̀tún mi, ọwọ́ ìṣẹ́gun, ni n óo fi gbé ọ ró. “Gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ pa ọ́ run ni n óo dójú tì, wọn óo sì dààmú. Àwọn tí ń bá ọ jà yóo di asán, wọn óo sì ṣègbé. O óo wá àwọn tí ń bá ọ jà tì, o kò ní rí wọn. Àwọn tí ó gbógun tì ọ́ yóo di òfo patapata. Nítorí èmi OLUWA Ọlọrun rẹ, ti di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, èmi ni mo sọ fún ọ pé kí o má bẹ̀rù, n óo ràn ọ́ lọ́wọ́.” Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, bí ẹ tilẹ̀ dàbí kòkòrò lásán, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, OLUWA ní òun óo ràn yín lọ́wọ́. Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà yín. Ó ní, “N óo ṣe yín bí ohun èlò ìpakà titun, tí ó mú, tí ó sì ní eyín, ẹ óo tẹ àwọn òkè ńlá mọ́lẹ̀, ẹ óo rún wọn wómúwómú; ẹ óo sì sọ àwọn òkè kéékèèké di fùlùfúlù. Ẹ óo fẹ́ wọn bí ọkà, atẹ́gùn yóo gbé wọn lọ, ìjì yóo sì fọ́n wọn ká. Ẹ̀yin óo yọ̀ ninu OLUWA ẹ óo sì ṣògo ninu Ẹni Mímọ́ Israẹli. “Nígbà tí àwọn talaka ati àwọn aláìní bá ń wá omi, tí omi kò sí, tí òùngbẹ ń gbẹ wọ́n, tí ọ̀nà ọ̀fun wọn gbẹ, èmi OLUWA yóo dá wọn lóhùn, èmi Ọlọrun Israẹli kò ní fi wọ́n sílẹ̀. N óo ṣí odò lórí àwọn òkè, ati orísun láàrin àwọn àfonífojì; n óo sọ aṣálẹ̀ di adágún odò, ilẹ̀ gbígbẹ yóo sì di orísun omi. N óo gbin igi kedari sinu aṣálẹ̀, pẹlu igi akasia ati igi mitili ati igi olifi. N óo gbin igi sipirẹsi sinu aṣálẹ̀, n óo gbin igi firi ati pine papọ̀. Kí àwọn eniyan lè rí i, kí wọn sì mọ̀, kí wọ́n rò ó wò, kí òye lè yé wọn papọ̀, pé ọwọ́ OLUWA ni ó ṣe èyí, Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ó ṣẹ̀dá rẹ̀.” OLUWA, Ọba Jakọbu, ní: “Ẹ̀yin oriṣa àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ ro ẹjọ́ yín, kí ẹ mú ẹ̀rí tí ó dájú wá lórí ohun tí ẹ bá ní sọ. Ẹ mú wọn wá, kí ẹ sì sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ fún wa; kí ẹ sọ àwọn ohun àtijọ́ fún wa. Kí á lè gbé wọn yẹ̀wò; kí á lè mọ àyọrísí wọn, tabi kí ẹ sọ àwọn ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ fún wa.” OLUWA ní, “Ẹ sọ ohun tí ń bọ̀ lẹ́yìn ọ̀la fún wa, kí á lè mọ̀ pé oriṣa ni yín; ẹ ṣe nǹkan rere tabi nǹkan burúkú kan, kí á rí i, kí ẹ̀rù sì bà wá. Ẹ wò ó! Òfo ni yín, òfo sì ni iṣẹ́ ọwọ́ yín, ẹni ìríra ni ẹni tí ó bá yàn yín. Mo ti gbé ẹnìkan dìde láti ìhà àríwá, ó sì ti dé. Láti ìlà oòrùn ni yóo ti pe orúkọ mi; yóo máa gún àwọn ọba mọ́lẹ̀ bì ìgbà tí wọ́n gún nǹkan ninu odó, àní, bí ìgbà tí amọ̀kòkò bá ń gún amọ̀. Ta ló kéde rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá, kí á lè mọ̀, ta ló sọ nípa rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ kí á lè sọ pé, ‘Olóòótọ́ ni?’ Kò sí ẹni tí ó sọ ọ́, kò sí ẹni tí ó kéde rẹ̀; ẹnìkankan kò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Èmi OLUWA ni mo ti kọ́kọ́ sọ fún Sioni, tí mo sì ròyìn ayọ̀ náà fún Jerusalẹmu. Nígbà tí mo wo ààrin àwọn wọnyi, kò sí olùdámọ̀ràn kan, tí ó lè dá mi lóhùn nígbà tí mo bá ní ìbéèrè. Wò ó! Ìtànjẹ lásán ni gbogbo wọn, òfo ni iṣẹ́ ọwọ́ wọn: Ẹ̀fúùfù lásán ni àwọn ère tí wọ́n gbẹ́.” OLUWA ní, “Wo iranṣẹ mi, ẹni tí mo gbéró, àyànfẹ́ mi, ẹni tí inú mi dùn sí. Mo ti jẹ́ kí ẹ̀mí mi bà lé e, yóo máa dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè. Kò ní kígbe, kò sì ní pariwo, kò ní jẹ́ kí á gbọ́ ohùn rẹ̀ ní ìta gbangba. Kò ní ṣẹ́ ọ̀pá ìyè tí ó tẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní pa iná fìtílà tí ń jò bẹ́lúbẹ́lú, yóo fi òtítọ́ dá ẹjọ́. Kò ní kùnà, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn rẹ̀ kò ní rẹ̀wẹ̀sì, títí yóo fi fìdí ìdájọ́ òdodo múlẹ̀ láyé. Àwọn erékùṣù ń retí òfin rẹ̀.” Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA Ọlọrun sọ; ẹni tí ó dá ojú ọ̀run tí ó sì ta á bí aṣọ, tí ó tẹ ayé, ati àwọn ohun tí ń hù jáde láti inú rẹ̀; ẹni tí ó fi èémí sinu àwọn eniyan tí ń gbé orí ilẹ̀; tí ó sì fi ẹ̀mí fún àwọn tí ó ń rìn lórí rẹ̀. Ó ní, “Èmi ni OLUWA, mo ti pè ọ́ ninu òdodo, mo ti di ọwọ́ rẹ mú, mo sì pa ọ́ mọ́. Mo ti fi ọ́ ṣe majẹmu fún aráyé, mo sì fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè; kí o lè la ojú àwọn afọ́jú, kí o lè yọ àwọn ẹlẹ́wọ̀n kúrò ni àhámọ́, kí o lè yọ àwọn tí ó jókòó ninu òkùnkùn kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n. “Èmi ni OLUWA, bẹ́ẹ̀ ni orúkọ mi; n kò ní fi ògo mi fún ẹlòmíràn, n kò sì ní fi ìyìn mi fún ère. Wò ó! Àwọn nǹkan àtijọ́ ti kọjá, àwọn nǹkan tuntun ni mò ń kéde nisinsinyii. Kí wọn tó yọjú jáde rárá, ni mo ti sọ fún ọ nípa wọn.” Ẹ kọ orin tuntun sí OLUWA; ẹ kọ orin ìyìn rẹ̀ láti òpin ayé. Ẹ̀yin èrò inú ọkọ̀ lójú agbami òkun, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu omi òkun; ati àwọn erékùṣù ati àwọn tí ń gbé inú wọn. Kí aṣálẹ̀ ati àwọn ìlú inú rẹ̀ kọ orin ìyìn sókè, ati àwọn abúlé agbègbè Kedari; kí àwọn ará ìlú Sela kọrin ayọ̀, kí wọn máa kọrin lórí àwọn òkè. Kí wọn fi ògo fún OLUWA, kí wọn kéde ìyìn rẹ̀ ní àwọn erékùṣù. OLUWA yọ jáde lọ bí alágbára ọkunrin, ó ru ibinu rẹ̀ sókè bí ọkunrin ogun, ó kígbe, ó sì bú ramúramù. Ó fihàn pé alágbára ni òun níwájú àwọn ọ̀tá rẹ̀. OLUWA ní: “Ó ti pẹ́ tí mo ti dákẹ́ jẹ́ẹ́, mo dákẹ́ jẹ́ẹ́, mo mára dúró. Ṣugbọn nisinsinyii, n óo kígbe, bí obinrin tí ń rọbí lọ́wọ́. N óo máa mí túpetúpe, n óo máa mí hẹlẹhẹlẹ. N óo sọ àwọn òkè gíga ati àwọn kéékèèké di ilẹ̀, n óo mú kí gbogbo ewéko orí wọn gbẹ; n óo sọ àwọn odò di erékùṣù, n óo sì mú kí àwọn adágún omi gbẹ. “N óo darí àwọn afọ́jú, n óo mú wọn gba ọ̀nà tí wọn kò mọ̀ rí, n óo tọ́ wọn sọ́nà, ní ọ̀nà tí wọn kò mọ̀ rí. N óo sọ òkùnkùn di ìmọ́lẹ̀ níwájú wọn, n óo sì sọ àwọn ibi tí ó rí pálapàla di títẹ́jú. N óo ṣe àwọn nǹkan, n kò sì ní kọ̀ wọ́n sílẹ̀. A óo ká àwọn tí ó gbójú lé ère lọ́wọ́ kò, ojú yóo sì tì wọ́n patapata àwọn tí ń wí fún ère gbígbẹ́ pé: ‘Ẹ̀yin ni Ọlọrun wa.’ ” OLUWA ní: “Gbọ́, ìwọ adití, sì wò ó, ìwọ afọ́jú, kí o lè ríran. Ta ni afọ́jú, bíkòṣe iranṣẹ mi? Ta sì ni adití, bíkòṣe ẹni tí mo rán níṣẹ́? Ta ni ó fọ́jú tó ẹni tí mo yà sọ́tọ̀, tabi ta ni ojú rẹ̀ fọ́ tó ti iranṣẹ OLUWA? Ó ń wo ọpọlọpọ nǹkan, ṣugbọn kò ṣe akiyesi wọn. Etí rẹ̀ là sílẹ̀, ṣugbọn kò gbọ́ràn.” Ó wu OLUWA láti gbé òfin rẹ̀ ga ati láti ṣe é lógo nítorí òdodo rẹ̀. Ṣugbọn a ti ja àwọn eniyan wọnyi lólè, a sì ti kó wọn lẹ́rù, a ti sé gbogbo wọn mọ́ inú ihò ilẹ̀, a sì ti fi wọ́n pamọ́ sinu ọgbà ẹ̀wọ̀n. A fogun kó wọn, láìsí ẹni tí yóo gbà wọ́n sílẹ̀, a kó wọn lẹ́rú, láìsí ẹnikẹ́ni tí yóo sọ pé: “Ẹ dá wọn pada.” Èwo ninu yín ló fetí sí èyí, tabi tí yóo farabalẹ̀ gbọ́ nítorí ẹ̀yìn ọ̀la? Ta ló fa Jakọbu lé akónilẹ́rù lọ́wọ́, ta ló sì fa Israẹli lé àwọn ọlọ́ṣà lọ́wọ́? Ṣebí OLUWA tí a ti ṣẹ̀ ni, ẹni tí wọ́n kọ̀, tí wọn kò rìn ní ọ̀nà rẹ̀; tí wọn kò sì pa òfin rẹ̀ mọ́. Nítorí náà ó jẹ́ kí wọ́n rí ibinu òun, ó sì fi agbára ogun rẹ̀ hàn wọ́n. Ó tanná ràn án lọ́tùn-ún lósì, sibẹ kò yé e; iná jó o, sibẹsibẹ kò fi ṣe àríkọ́gbọ́n. Ṣugbọn nisinsinyii, Jakọbu, gbọ́ nǹkan tí OLUWA ẹlẹ́dàá rẹ wí, Israẹli, gbọ́ ohun tí ẹni tí ó dá ọ sọ. Ó ní, “Má bẹ̀rù, nítorí mo ti rà ọ́ pada; mo ti pè ọ́ ní orúkọ rẹ, èmi ni mo ni ọ́. Nígbà tí o bá ń la ibú omi kọjá, n óo wà pẹlu rẹ; nígbà tí o bá la odò ńlá kọjá, kò ní bò ọ́ mọ́lẹ̀, nígbà tí o bá ń kọjá ninu iná, kò ní jó ọ. Ahọ́n iná kò ní jó ọ run. Nítorí èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli, Olùgbàlà rẹ. Mo fi Ijipti, lélẹ̀, láti rà ọ́ pada, mo sì fi Etiopia ati Seba lélẹ̀ mo ti fi ṣe pàṣípààrọ̀ rẹ. Nítorí pé o ṣọ̀wọ́n lójú mi, o níyì, mo sì fẹ́ràn rẹ, mo fi àwọn eniyan rọ́pò rẹ; mo sì fi ẹ̀mí àwọn orílẹ̀-èdè dípò ẹ̀mí rẹ. Má bẹ̀rù nítorí mo wà pẹlu rẹ, n óo kó àwọn ọmọ rẹ wá láti ìlà oòrùn, n óo sì ko yín jọ láti ìwọ̀ oòrùn. N óo pàṣẹ fún ìhà àríwá pé, ‘Dá wọn sílẹ̀.’ N óo sọ fún ìhà gúsù pé, ‘O kò gbọdọ̀ dá wọn dúró.’ Kó àwọn ọmọ mi ọkunrin wá láti òkèèrè, sì kó àwọn ọmọ mi obinrin wá láti òpin ayé, gbogbo àwọn tí à ń fi orúkọ mi pè, àwọn tí mo dá fún ògo mi, àwọn tí mo fi ọwọ́ mi ṣẹ̀dá wọn.” Ẹ mú àwọn eniyan mi jáde, àwọn tí wọ́n ní ojú, ṣugbọn tí ojú wọn ti fọ́, wọ́n ní etí, ṣugbọn etí wọn ti di. Jẹ́ kí gbogbo orílẹ̀-èdè péjọ, kí àwọn eniyan àgbáyé parapọ̀. Èwo ninu wọn ni ó lè kéde irú àsọtẹ́lẹ̀ yìí, tí ó lè fi àwọn ohun àtijọ́ hàn wá; kí wọn pe ẹlẹ́rìí wọn wá, kí á lè mọ̀ pé ẹjọ́ wọn tọ́, kí àwọn ẹlòmíràn lè gbọ́, kì wọn sì jẹ́rìí pé, “Òtítọ́ ni.” OLUWA ní, “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi, ẹ̀yin ni iranṣẹ mi tí mo yàn; kí ẹ lè mọ̀ mí, kí ẹ sì gbà mí gbọ́, kí ó sì ye yín pé, Èmi ni. A kò dá Ọlọrun kankan ṣáájú mi, òmíràn kò sì ní wáyé lẹ́yìn mi. “Èmi ni OLUWA, kò sí olùgbàlà kan, yàtọ̀ sí mi. Mo ti sọ̀rọ̀ ìṣípayá, mo ti gba eniyan là, mo sì ti kéde, nígbà tí kò sí Ọlọrun àjèjì láàrin yín; ẹ̀yin sì ni ẹlẹ́rìí mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Èmi ni Ọlọrun, láti ìsinsìnyìí lọ, Èmi ni. Kò sí ẹnìkan tí ó lè gba eniyan kalẹ̀ lọ́wọ́ mi: Ta ni le dínà ohun tí mo bá níí ṣe?” OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli, Olùràpadà yín, ní, “N óo ranṣẹ sí Babiloni nítorí yín, n óo dá gbogbo ọ̀pá ìlẹ̀kùn ibodè, ariwo ẹ̀rín àwọn ará Kalidea yóo sì di ẹkún. Èmi ni OLUWA, Ẹni Mímọ́ yín, Ẹlẹ́dàá Israẹli, Ọba yín.” OLUWA tí ó la ọ̀nà sí ojú òkun, tí ó la ọ̀nà lórí agbami ńlá; ẹni tí ó kó kẹ̀kẹ́ ogun ati ẹṣin jáde, ogun, ati àwọn ọmọ-ogun; wọ́n dùbúlẹ̀ wọn kò lè dìde mọ́, wọ́n kú bí iná fìtílà. ÓLUWA ní, “Ẹ gbàgbé àwọn ohun àtijọ́, kí ẹ sì mú ọkàn kúrò ninu ohun tí ó ti kọjá. Ẹ wò ó! Mò ń ṣe nǹkan titun ó ti yọ jáde nisinsinyii, àbí ẹ kò ṣe akiyesi rẹ̀? N óo la ọ̀nà ninu aginjù, n óo sì mú kí omi máa ṣàn ninu aṣálẹ̀. Àwọn ẹranko ìgbẹ́ yóo máa yìn mí lógo, ati àwọn ọ̀fàfà ati ògòǹgò; nítorí pé mo ti ṣe odò ńlá fún wọn ninu aṣálẹ̀, kí àwọn àyànfẹ́ mi lè máa rí omi mu: Àwọn tí mo fọwọ́ mi dá fún ara mi, kí wọ́n lè kéde ògo mi. “Sibẹsibẹ, ẹ kò ké pè mí, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, ọ̀rọ̀ mi ti su yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli. Ẹ kò wá fi aguntan rúbọ sí mi, tabi kí ẹ wá fi ẹbọ rírú bu ọlá fún mi. N kò fi tipátipá mu yín rúbọ, bẹ́ẹ̀ ni n kò sọ pé dandan ni kí ẹ mú turari wá. Ẹ kò fowó yín ra turari olóòórùn dídùn fún mi, tabi kí ẹ fi ọ̀rá ẹbọ yín tẹ́ mi lọ́rùn. Kàkà bẹ́ẹ̀ ẹ̀ ń fi ẹ̀ṣẹ̀ yín yọ mí lẹ́nu, ẹ sì ń dààmú mi pẹlu àìdára yín. Èmi, èmi ni mo pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́, nítorí ti ara mi; n kò sì ní ranti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín mọ́. “Ẹ rán mi létí ọ̀rọ̀ yín kí á jọ ṣàríyànjiyàn; ẹ ro ẹjọ́ tiyín, kí á lè da yín láre. Baba ńlá yín àkọ́kọ́ ṣẹ̀, àwọn aṣiwaju yín náà sì ṣẹ̀ mí. Nítorí náà mo sọ àwọn olórí ibi mímọ́ mi di aláìmọ́, mo fi Jakọbu sílẹ̀ fún ìparun; mo sì sọ Israẹli di ẹni ẹ̀sín.” OLUWA ní: “Ṣugbọn nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu iranṣẹ mi ẹ̀yin ọmọ Israẹli, àyànfẹ́ mi. Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA, Ẹlẹ́dàá yín wí, ẹni tí ó ṣẹ̀dá yín láti inú oyún, tí yóo sì ràn yín lọ́wọ́: Ẹ má bẹ̀rù ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, iranṣẹ mi, Jeṣuruni, ẹni tí mo yàn. “N óo tú omi sórí ilẹ̀ tí òùngbẹ ń gbẹ n óo sì ṣe odò sórí ilẹ̀ gbígbẹ. N óo tú ẹ̀mí mi sórí àwọn ọmọ yín, n óo da ibukun mi sórí arọmọdọmọ yín, wọn óo rúwé bíi koríko inú omi àní, bíi igi wilo lẹ́bàá odò tí ń ṣàn. “Ẹnìkan yóo wí pé, ‘OLUWA ló ni mí.’ Ẹnìkejì yóo pe ara rẹ̀ ní orúkọ Jakọbu. Ẹlòmíràn yóo kọ ‘Ti OLUWA ni’ sí apá rẹ̀ yóo máa fi orúkọ Israẹli ṣe àpèjá orúkọ rẹ̀.” Gbọ́ ohun tí OLUWA, ọba Israẹli ati Olùràpadà rẹ̀ wí, OLUWA àwọn ọmọ ogun, ó ní, “Èmi ni ẹni ìbẹ̀rẹ̀ ati ẹni òpin; lẹ́yìn mi, kò sí Ọlọrun mìíràn. Ta ni ó dàbí mi? Kí olúwarẹ̀ sọ̀rọ̀ kí ó kéde rẹ̀ níwájú mi. Ẹni tí ó bá ti kéde láti ìbẹ̀rẹ̀, nípa àwọn nǹkan tí yóo ṣẹlẹ̀, kí wọn sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ fún wa. Má bẹ̀rù, má sì fòyà. Ṣebí mo ti sọ fún ọ tipẹ́, mo ti kéde rẹ̀, ìwọ sì ni ẹlẹ́rìí mi: Ǹjẹ́ Ọlọrun mìíràn wà lẹ́yìn mi? Kò tún sí àpáta kan mọ́, n kò mọ ọ̀kan kan.” Asán ni àwọn tí ń gbẹ́ ère, ohun tí inú wọn dùn sí kò lérè. Àwọn tí ń jẹ́rìí wọn kò ríran, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ nǹkan, ojú ìbá le tì wọ́n. Ta ló ṣe oriṣa, ta ló sì yá ère tí kò lérè? Ojú yóo ti gbogbo wọn; eniyan sá ni wọ́n. Ẹ jẹ́ kí gbogbo wọn pésẹ̀, kí wọ́n jáde wá. Ìpayà yóo bá wọn, ojú yóo sì ti gbogbo wọn papọ̀. Alágbẹ̀dẹ a mú irin, a fi sinu iná, a máa fi ọmọ owú lù ú, a sì fi agbára rẹ̀ rọ ọ́ bí ó ti fẹ́ kí ó rí. Ebi a pa á, àárẹ̀ a sì mú un; kò ní mu omi, a sì máa rẹ̀ ẹ́. Agbẹ́gilére a ta okùn sára igi, a fi ẹfun fa ìlà sí i, a fi ìwọ̀n wọ̀n ọ́n, a sì gbẹ́ ẹ bí eniyan: ẹwà rẹ̀ a dàbí ti eniyan, wọn a sì kọ́lé fún un. Ó lè gé igi kedari lulẹ̀, tabi kí ó gbin igi Sipirẹsi, tabi igi Oaku, kí ó jẹ́ kí ó dàgbà láàrin àwọn igi inú igbó. Ó sì lè gbin igi kedari kan, omi òjò a sì mú kí ó dàgbà. Lẹ́yìn náà igi yìí di igi ìdáná: Eniyan óo gé ninu rẹ̀, yóo fi dáná yá; yóo gé ninu rẹ̀ yóo fi dáná oúnjẹ; yóo gé ninu rẹ̀, yóo fi gbẹ́ ère, yóo máa bọ ọ́. Eniyan á wá sọ igi lásán tí ó gbẹ́ di oriṣa, á sì máa foríbalẹ̀ fún un. Yóo fi ìdajì rẹ̀ dáná, yóo fi se oúnjẹ, yóo fi se ẹran rẹ̀ pẹlu. Yóo jẹun, yóo jẹran, yóo yó; yóo tún yáná. Yóo ní, “Áà! Ooru mú mi nítorí mo rí iná yá.” Yóo fi èyí tí ó kù gbẹ́ ère oriṣa rẹ̀, yóo máa foríbalẹ̀ fún un, yóo máa bọ ọ́, yóo máa gbadura sí i pé, “Gbà mí, nítorí ìwọ ni Ọlọrun mi.” Wọn kò mọ nǹkan, bẹ́ẹ̀ ni òye kò yé wọn. Nǹkankan ti bò wọ́n lójú kí wọn má baà lè ríran; ó sì ti sé wọn lọ́kàn kí òye má baà yé wọn. Kò sí ẹni tí ó ronú wò, tabi tí ó ní ìmọ̀ tabi òye, láti wí pé: “Ìdajì igi yìí ni mo fi dáná tí mo fi se oúnjẹ, tí mo sì fi se ẹran tí mo jẹ. Kí ló wá dé tí n óo ṣe fi ìyókù gbẹ́ ère kí n máa bọ ọ́? Ṣé ìtì igi lásán ló yẹ kí n máa foríbalẹ̀ fún, kí n máa bọ?” Kò yàtọ̀ sí ẹni tí ń pe eérú ní oúnjẹ. Èrò ẹ̀tàn ti ṣì í lọ́nà, kò sì lè gba ara rẹ̀ kalẹ̀ tabi kí ó bi ara rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ irọ́ kọ́ ni ohun tí ó wà lọ́wọ́ mi yìí?” Jakọbu, ranti àwọn nǹkan wọnyi, nítorí pé iranṣẹ mi ni ọ́, ìwọ Israẹli. Èmi ni mo ṣẹ̀dá rẹ, iranṣẹ mi ni ọ́, n kò jẹ́ gbàgbé rẹ, Israẹli. Mo ti ká àìdára rẹ kúrò bí awọsanma, mo ti gbá ẹ̀ṣẹ̀ rẹ dànù bí ìkùukùu. Pada sọ́dọ̀ mi, nítorí mo ti rà ọ́ pada. Ẹ hó ìhó ayọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, nítorí OLUWA ti ṣe é. Ẹ pariwo, ẹ̀yin ìsàlẹ̀ ilẹ̀. Ẹ kọrin, ẹ̀yin òkè ńlá, ìwọ igbó ati igi inú rẹ̀, nítorí OLUWA ti ra Jakọbu pada, yóo sì ṣe ara rẹ̀ lógo ní Israẹli. Gbọ́ ohun tí OLUWA, Olùràpadà rẹ wí, ẹni tí ó ṣẹ̀dá rẹ láti inú oyún. Ó ní, “Èmi ni OLUWA, tí mo dá ohun gbogbo. Èmi nìkan ni mo tẹ́ ojú ọ̀run, tí mo sì dá ilẹ̀ ayé tẹ́, èmi tí mo sọ àmì àwọn tí ń woṣẹ́ èké di asán, tí mo sì sọ àwọn aláfọ̀ṣẹ di òmùgọ̀. Mo yí ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n po mo sì sọ ọgbọ́n wọn di òmùgọ̀. Èmi tí mo jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ iranṣẹ mi, tí mo sì mú ìmọ̀ àwọn ikọ̀ mi ṣẹ, èmi tí mo wí fún Jerusalẹmu pé, ‘Àwọn eniyan yóo máa gbé inú rẹ,’ tí mo sì wí fún àwọn ìlú Juda pé, ‘A óo tún odi yín mọ, n óo sì tún yín kọ́.’ Èmi tí mo pàṣẹ fún agbami òkun pé, ‘Gbẹ! n óo mú kí àwọn odò rẹ gbẹ;’ èmi tí mo sọ fún Kirusi pé: ‘Ìwọ ni ọba tí n óo yàn tí yóo mú gbogbo ìpinnu mi ṣẹ;’ tí mo sọ fún Jerusalẹmu pé: ‘A óo tún odi rẹ̀ mọ,’ tí mo sì sọ fún Tẹmpili pé, ‘A óo tún fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀.’ ” Ohun tí OLUWA sọ fún kirusi, ẹni tí ó fi àmì òróró yàn nìyí: Ẹni tí OLUWA di ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú, tí ó lò, láti rẹ àwọn orílẹ̀-èdè sílẹ̀ níwájú rẹ̀, láti tú àmùrè àwọn ọba, láti ṣí àwọn ìlẹ̀kùn níwájú rẹ̀, kí ẹnubodè má lè tì. OLUWA ní, “N óo lọ ṣáájú rẹ, n óo sọ àwọn òkè ńlá di pẹ̀tẹ́lẹ̀; n óo fọ́ ìlẹ̀kùn idẹ, n óo sì gé ọ̀pá ìlẹ̀kùn irin. N óo fún ọ ní ìṣúra tí wọ́n fi pamọ́ sinu òkùnkùn, ati àwọn nǹkan tí wọ́n kó pamọ́ síkọ̀kọ̀; kí o lè mọ̀ pé èmi, OLUWA, Ọlọrun Israẹli, ni mo pè ọ́ ní orúkọ rẹ. Nítorí Jakọbu, iranṣẹ mi, ati Israẹli, àyànfẹ́ mi, mo pè ọ́ ní orúkọ rẹ. Mo pe orúkọ rẹ ní àpèjá, bẹ́ẹ̀ ni o kò mọ̀ mí. “Èmi ni OLUWA kò sí ẹlòmíràn, kò sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn mi. Mo dì ọ́ ní àmùrè bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o kò mọ̀ mí. Kí àwọn eniyan lè mọ̀ pé, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀, kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi. Èmi ni OLUWA, kò tún sí ẹlòmíràn. Èmi ni mo dá ìmọ́lẹ̀ ati òkùnkùn, èmi ni mo dá alaafia ati àjálù: Èmi ni OLUWA tí mo ṣe gbogbo nǹkan wọnyi. Rọ òjò sílẹ̀, ìwọ ọ̀run, kí ojú ọ̀run rọ̀jò òdodo sílẹ̀. Jẹ́ kí ilẹ̀ lanu, kí ìgbàlà lè yọ jáde. Jẹ́ kí ó mú kí òdodo yọ jáde pẹlu, èmi OLUWA ni mo ṣẹ̀dá rẹ̀ bẹ́ẹ̀. “Ẹni tí ń bá ẹlẹ́dàá rẹ̀ jà gbé! Ìkòkò tí ń bá amọ̀kòkò jà. Ṣé amọ̀ lè bèèrè lọ́wọ́ ẹni tí ń mọ ọ́n pé: ‘Kí ni ò ń mọ?’ Tabi kí ó sọ fún un pé, ‘Nǹkan tí ò ń mọ kò ní ìgbámú?’ Ẹnìkan lè bi baba rẹ̀ pé: ‘Irú kí ni o bí?’ Tabi kí ó bi ìyá rẹ̀ léèrè pé: ‘Irú ọmọ wo ni o bí yìí?’ Olúwarẹ̀ gbé!” OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli, ẹlẹ́dàá rẹ ni, “Ṣé ẹ óo máa bi mí ní ìbéèrè nípa àwọn ọmọ mi ni, tabi ẹ óo máa pàṣẹ fún mi nípa iṣẹ́ ọwọ́ mi? Èmi ni mo dá ayé, tí mo dá eniyan sórí rẹ̀. Ọwọ́ mi ni mo fi ta ojú ọ̀run bí aṣọ, tí mo sì pàṣẹ fún oòrùn, òṣùpá ati àwọn ìràwọ̀. Èmi ni mo gbé Kirusi dìde ninu òdodo mi, n óo mú kí ó ṣe nǹkan bí ó ti tọ́; òun ni yóo tún ìlú mi kọ́, yóo sì dá àwọn eniyan mi tí wọ́n wà ní ìgbèkùn sílẹ̀, láìgba owó ati láìwá èrè kan.” OLUWA àwọn ọmọ ogun ló sọ bẹ́ẹ̀. Ó ní, “Àwọn ọrọ̀ ilẹ̀ Ijipti ati àwọn ẹrù ilẹ̀ Etiopia, ati àwọn ọkunrin Seba tí wọn ṣígbọnlẹ̀, wọn óo tọ̀ ọ́ wá, wọn óo di tìrẹ, wọn óo sì máa tẹ̀lé ọ. Wọn óo wá, pẹlu ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ lẹ́sẹ̀ wọn, wọn óo sì wólẹ̀ fún ọ. Wọn óo máa bẹ̀ ọ́ pé, ‘Lọ́dọ̀ rẹ nìkan ni Ọlọrun wà, kò tún sí Ọlọrun mìíràn. Kò sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn rẹ.’ ” Nítòótọ́, ìwọ ni Ọlọrun tí ó ń fi ara pamọ́, Ọlọrun Israẹli, Olùgbàlà. Gbogbo àwọn oriṣa ni a óo dójú tì, ìdààmú yóo sì bá wọn. Gbogbo àwọn tí ń gbẹ́ ère yóo bọ́ sinu ìdààmú papọ̀. Ṣugbọn OLUWA gba Israẹli là, títí ayé sì ni ìgbàlà rẹ̀. Ojú kò ní tì ọ́, bẹ́ẹ̀ ni o kò ní dààmú, títí lae. Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí, OLUWA tí ó dá ọ̀run. (Òun ni Ọlọrun.) Òun ni ó dá ilẹ̀, tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, kò dá a ninu rúdurùdu, ṣugbọn ó dá a kí eniyan lè máa gbé inú rẹ̀ Ó ní, “Èmi ni OLUWA, kò sí Ọlọrun mìíràn. N kò sọ ọ́ níkọ̀kọ̀, ninu òkùnkùn. N kò sọ fún arọmọdọmọ Jakọbu pé: ‘Ẹ máa wá mi ninu rúdurùdu.’ Òtítọ́ ni Èmi OLUWA sọ. Ohun tí ó tọ́ ni mò ń kéde.” OLUWA ní: “Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ wá, ẹ jọ súnmọ́ bí, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ kù ninu àwọn orílẹ̀-èdè. Aláìlóye ni àwọn tí ń gbẹ́ ère igi lásán kiri, tí wọ́n sì ń gbadura sí oriṣa tí kò lè gbànìyàn là. Ẹ sọ̀rọ̀ jáde, kí ẹ sì ro ẹjọ́ tiyín, jẹ́ kí wọ́n jọ gbìmọ̀ pọ̀. Ta ló sọ èyí láti ìgbà laelae? Ta ló kéde rẹ̀ láti ìgbà àtijọ́? Ṣebí èmi OLUWA ni? Kò tún sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn mi. Ọlọrun Olódodo ati Olùgbàlà kò tún sí ẹnìkan mọ́, àfi èmi. “Ẹ yipada sí mi kí á gbà yín là, gbogbo ẹ̀yin òpin ayé. Nítorí èmi ni Ọlọrun, kò tún sí ẹlòmíràn mọ́. Mo ti fi ara mi búra, mo sì fi ẹnu mi sọ̀rọ̀ pẹlu òtítọ́ inú, ọ̀rọ̀ tí kò ní yipada: ‘Gbogbo orúnkún ni yóo wólẹ̀ fún mi, èmi ni gbogbo eniyan yóo sì búra pé àwọn óo máa sìn.’ “Nípa èmi nìkan ni àwọn eniyan yóo máa pé, ‘Ninu OLUWA ni òdodo ati agbára wà.’ Gbogbo àwọn tí ń bá a bínú yóo pada wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹlu ìtìjú. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli yóo ṣẹgun, wọn yóo sì ṣògo ninu OLUWA. “Oriṣa Bẹli tẹríba, oriṣa Nebo doríkodò. Orí àwọn ẹran ọ̀sìn ati mààlúù ni àwọn oriṣa wọn wà. Àwọn nǹkan tí ẹ̀ ń rù kiri wá di ẹrù, tí àwọn ẹranko tí ó ti rẹ̀ ń rù. Àwọn mejeeji jọ tẹríba, wọ́n jọ doríkodò, wọn ò lè gba àwọn ẹrù wọn kalẹ̀. Àwọn pàápàá yóo lọ sí ìgbèkùn. “Ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin ará ilé Jakọbu, ati gbogbo ará ilé Israẹli tí ó ṣẹ́kù; ẹ̀yin tí mo pọ̀n láti ọjọ́ tí wọ́n ti bi yín, tí mo sì gbé láti inú oyún. Èmi náà ni, títí di ọjọ́ ogbó yín, n óo gbé yín títí tí ẹ óo fi hewú lórí. Èmi ni mo da yín, n óo sì máa tọ́jú yín, n óo máa gbé yín, n óo sì gbà yín là. “Ta ni ẹ óo fi mí wé? Ta ni ẹ óo fi díwọ̀n mi? Ta ni ẹ lè fi wé mi, kí á lè jọ jẹ́ bákan náà? Àwọn kan ń kó ọpọlọpọ wúrà jáde ninu àpò, wọ́n sì ń wọn fadaka lórí ìwọ̀n. Wọ́n sanwó ọ̀yà fún alágbẹ̀dẹ wúrà, ó bá wọn fi dá oriṣa. Wọ́n wá ń foríbalẹ̀ fún un, wọ́n ń sìn ín. Wọn á gbé e lé èjìká wọn, wọn á gbé e sípò rẹ̀, á sì dúró kabẹ̀. Kò ní le kúrò níbẹ̀ lọ sí ibìkankan. Bí eniyan bá ké pè é, kò lè gbọ́, kò lè yọ eniyan ninu ìṣòro rẹ̀. “Ẹ ranti èyí, kí ẹ dà á rò, ẹ fi ọkàn rò ó, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀. Ẹ ranti àwọn nǹkan ti àtijọ́, nítorí pé èmi ni Ọlọrun, kò sí Ọlọrun mìíràn mọ́. Èmi ni Ọlọrun, kò sí ẹni tí ó dà bí mi. Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni èmi tíí sọ ohun tí ó gbẹ̀yìn. Láti ìgbà àtijọ́, ni mo tí ń sọ àwọn nǹkan tí kò ì tíì ṣẹlẹ̀. Èmi a máa sọ pé: ‘Àbá mi yóo ṣẹ, n óo sì mú ìpinnu mi ṣẹ.’ Mo pe idì láti ìlà oòrùn, mo sì ti pe ẹni tí yóo mú àbá mi ṣẹ láti ilẹ̀ òkèèrè wá. Mo ti sọ̀rọ̀, n óo sì mú un ṣẹ, mo ti ṣe ìpinnu, n óo sì ṣe é. “Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin aláìgbọràn, ẹ̀yin tí ẹ jìnnà sí ìgbàlà. Mo mú ìdáǹdè mi wá sí tòsí, kò jìnnà mọ́, ìgbàlà mi kò ní pẹ́ dé. N óo fi ìgbàlà mi sí Sioni, fún Israẹli, ògo mi.” Sọ̀kalẹ̀ kí o jókòó ninu eruku, ìwọ Babiloni. Jókòó ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀, láìsí ìtẹ́-ọba, ìwọ ọmọbinrin Kalidea. A kò ní pè ọ́ ní ẹlẹgẹ́ ati aláfẹ́ mọ́. Gbé ọlọ kí o máa lọ ọkà, ṣí aṣọ ìbòjú rẹ kúrò, ká aṣọ rẹ sókè, kí o ṣí ẹsẹ̀ rẹ sílẹ̀, kí o sì la odò kọjá. A óo tú ọ sí ìhòòhò, a óo sì rí ìtìjú rẹ. N óo gbẹ̀san, n kò sì ní dá ẹnìkan kan sí. Olùràpadà wa, tí ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun, ni Ẹni Mímọ́ Israẹli. OLUWA wí nípa Kalidea pé: “Jókòó kí o dákẹ́ jẹ́ẹ́, kí o sì wọ inú òkùnkùn lọ, ìwọ ọmọbinrin Kalidea. Nítorí a kò ní pè ọ́ ní ayaba àwọn orílẹ̀-èdè mọ́. Inú bí mi sí àwọn eniyan mi, mo sì sọ nǹkan ìní mi di ohun ìríra. Mo fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́, o kò ṣàánú wọn. O di àjàgà wúwo rẹ mọ́ àwọn arúgbó lọ́rùn. O sọ pé ìwọ ni o óo máa jẹ́ ayaba títí lae, nítorí náà o kò kó àwọn nǹkan wọnyi lékàn, o kò sì ranti ìgbẹ̀yìn wọn. “Nítorí náà, gbọ́ nisinsinyii, ìwọ tí o fẹ́ràn afẹ́ ayé, tí o jókòó láìléwu, tí ò ń sọ lọ́kàn rẹ pé, ‘Èmi nìkan ni mo wà, kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi. N kò ní di opó, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní ṣòfò ọmọ.’ Ọ̀fọ̀ mejeeji ni yóo ṣe ọ́ lójijì, lọ́jọ́ kan náà: o óo ṣòfò ọmọ, o óo sì di opó, ibi yìí yóo dé bá ọ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Ò báà lóṣó, kí o lájẹ̀ẹ́, kí àfọ̀ṣẹ rẹ sì múná jù bẹ́ẹ̀ lọ. “Ọkàn rẹ balẹ̀ ninu iṣẹ́ ibi rẹ, o ní ẹnìkan kò rí ọ. Ọgbọ́n ati ìmọ̀ rẹ mú ọ ṣìnà, ò ń sọ ní ọkàn rẹ pé, ‘Èmi nìkan ní mo wà. Kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.’ Ṣugbọn ibi yóo dé bá ọ, tí o kò ní lè dáwọ́ rẹ̀ dúró; àjálù yóo dé bá ọ, tí o kò ní lè ṣe ètùtù rẹ̀; ìparun yóo dé bá ọ lójijì, tí o kò ní mọ nǹkankan nípa rẹ̀. Múra sí àfọ̀ṣẹ rẹ, sì múra si oṣó ṣíṣẹ́ jọ, tí o ti dáwọ́ lé láti kékeré, bóyá o óo tilẹ̀ yege, tabi bóyá o sì lè dẹ́rùba eniyan. Ọpọlọpọ ìmọ̀ràn tí wọn fún ọ ti sú ọ; jẹ́ kí wọn dìde nílẹ̀ kí wọ́n gbà ọ́ wàyí, àwọn tí ó ń wojú ọ̀run, ati àwọn awòràwọ̀; tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ọ, nígbà tí oṣù bá ti lé. “Wò ó! Wọ́n dàbí àgékù koríko, iná ni yóo jó wọn ráúráú, wọn kò sì ní lè gba ara wọn kalẹ̀, ninu ọ̀wọ́ iná. Eléyìí kì í ṣe iná tí eniyan ń yá, kì í ṣe iná tí eniyan lè jókòó níwájú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ rí sí ọ, àwọn tí ẹ ti jọ ń ṣòwò pọ̀ láti ìgbà èwe rẹ. Olukuluku wọn ti ṣìnà lọ, kò sí ẹni tí yóo gbà ọ́ sílẹ̀.” Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin ará ilé Jakọbu, ẹ̀yin tí à ń fi orúkọ Israẹli pè, ọmọ bíbí inú Juda, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń forúkọ OLUWA búra, tí ẹ jẹ́wọ́ Ọlọrun Israẹli, ṣugbọn tí kì í ṣe pẹlu òdodo tabi òtítọ́. Ẹ̀ ń pe ara yín ní ará ìlú mímọ́, ẹ fẹ̀yìn ti Ọlọrun Israẹli, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun. OLUWA ní, “Láti ìgbà àtijọ́ ni mo ti kéde, àwọn nǹkan tí yóo ṣẹlẹ̀, èmi ni mo sọ wọ́n jáde, tí mo sì fi wọ́n hàn. Lójijì mo ṣe wọ́n, nǹkan tí mo sọ sì ṣẹ. Nítorí mo mọ̀ pé alágídí ni yín, olóríkunkun sì ni yín pẹlu. Mo ti sọ fun yín láti ọjọ́ pípẹ́: kí wọn tó ṣẹlẹ̀, mo ti kéde wọn fun yín, kí ẹ má baà sọ pé, ‘oriṣa wa ni ó ṣe wọ́n, àwọn ère wa ni ó pàṣẹ pé kí wọn ṣẹlẹ̀.’ “Ẹ ti fetí ara yín gbọ́, nítorí náà, ẹ wo gbogbo èyí, ṣé ẹ kò ní kéde rẹ̀? Láti àkókò yìí lọ, n óo mú kí ẹ máa gbọ́ nǹkan tuntun, àwọn nǹkan tí ó farapamọ́ tí ẹ kò mọ̀. Kò tíì pẹ́ tí a dá wọn, ẹ kò gbọ́ nípa wọn rí, àfi òní. Kí ẹ má baà wí pé: Wò ó, a mọ̀ wọ́n. Ẹ kò gbọ́ ọ rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀. Ọjọ́ ti pẹ́ tí a ti di yín létí, nítorí mo mọ̀ pé ẹ óo hùwà àgàbàgebè, ọlọ̀tẹ̀ ni orúkọ tí mo mọ̀ yín mọ̀, láti ìgbà tí ẹ ti jáde ninu oyún. “Mo dáwọ́ ibinu mi dúró ná, nítorí orúkọ mi, nítorí ìyìn mi ni mo ṣe dá a dúró fun yín, kí n má baà pa yín run. Mo ti fọ̀ ọ́ mọ́, ṣugbọn kì í ṣe bí a tií fọ fadaka, mo dán yín wò ninu iná ìpọ́njú. Nítorí tèmi, àní nítorí tèmi ni mo ṣe ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí kí ni ìdí rẹ̀ tí orúkọ mi yóo ṣe díbàjẹ́, n kò ní gbé ògo mi fún ẹlòmíràn. “Tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi ìwọ Jakọbu, ìwọ Israẹli, ẹni tí mo pè, Èmi ni ẹni ìbẹ̀rẹ̀, èmi sì ni ẹni òpin. Ọwọ́ mi ni mo fi fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, ọwọ́ ọ̀tún mi ni mo fi ta awọsanma sójú ọ̀run. Nígbà tí mo pè wọ́n, gbogbo wọn jọ yọ síta. “Gbogbo yín, ẹ péjọ, kí ẹ gbọ́, èwo ninu wọn ni ó kéde nǹkan wọnyi? OLUWA fẹ́ràn rẹ̀, yóo mú ìfẹ́ inú rẹ̀ ṣẹ lórí Babiloni, yóo sì gbógun ti àwọn ará Kalidea. Èmi, àní èmi pàápàá ni mo sọ̀rọ̀, tí mo pè é, èmi ni mo mú un wá, yóo sì ṣe àṣeyege ninu àdáwọ́lé rẹ̀. Ẹ súnmọ́ mi, kí ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, láti ìbẹ̀rẹ̀ wá, n kò sọ̀rọ̀ ní àṣírí, láti ìgbà tí ọ̀rọ̀ náà ti ṣe ni mo ti wà níbẹ̀.” Nisinsinyii, OLUWA, Ọlọrun, ati Ẹ̀mí rẹ̀ ti rán mi. OLUWA, Olùràpadà rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli, ní, “Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ, tí ń kọ́ ọ ní ohun tí yóo ṣe ọ́ ní anfaani, tí ń darí rẹ, sí ọ̀nà tí ó yẹ kí o gbà. “Ìbá jẹ́ pé o ti fetí sí òfin mi, alaafia rẹ ìbá máa ṣàn bí odò, òdodo rẹ ìbá lágbára bi ìgbì omi òkun. Àwọn ọmọ rẹ ìbá pọ̀ bí iyanrìn, arọmọdọmọ rẹ ìbá pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀ tí kò lóǹkà. Orúkọ wọn kì bá tí parẹ́ títí ayé, bẹ́ẹ̀ ni kì bá tí parun lae níwájú mi.” Ẹ jáde kúrò ní Babiloni, ẹ sá kúrò ní Kalidea, ẹ sọ ọ́ pẹlu ayọ̀, ẹ kéde rẹ̀, ẹ máa ròyìn rẹ̀ lọ títí dè òpin ayé, pé “OLUWA ti ra Jakọbu iranṣẹ rẹ̀ pada.” Òùngbẹ kò gbẹ wọ́n, nígbà tí ó mú wọn la inú aṣálẹ̀ kọjá, ó tú omi jáde fún wọn láti inú àpáta, ó la àpáta, omi sì tú jáde. OLUWA sọ pé, “Kò sí alaafia fún àwọn eniyan burúkú.” Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ilẹ̀ etí òkun. Ẹ fetí sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ mi, ẹ̀yin ará ilẹ̀ òkèèrè, láti inú oyún ni OLUWA ti pè mí, láti inú ìyá mi wá ni ó ti dárúkọ mi. Ó ṣe ẹnu mi bí idà mímú, ó fi mí pamọ́ sí ibi òjìji ọwọ́ rẹ̀, ó ṣe mí ní ọfà tí ó mú, ó fi mí pamọ́ sinu apó rẹ̀. Ó sọ fún mi pé, “Iranṣẹ mi ni ọ́, ìwọ Israẹli, àwọn eniyan óo máa yìn mí lógo nítorí rẹ.” Ṣugbọn mo dáhùn pé, “Mo ti ṣiṣẹ́ àṣedànù. Mo ti lo agbára mi ṣòfò, mo ti fi ṣe àṣedànù, sibẹsibẹ ẹ̀tọ́ mi ń bẹ lọ́dọ̀ OLUWA.” Ẹ̀san mi ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọrun mi, yóo san án fún mi. Nisinsinyii, OLUWA, tí ó ṣẹ̀dá mi ninu oyún, kí n lè jẹ́ iranṣẹ rẹ̀, láti mú Jakọbu pada tọ̀ ọ́ wá, ati láti mú kí Israẹli kórajọ pọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀; nítorí mo níyì lójú OLUWA, Ọlọrun mi sì ti di agbára mi. OLUWA ní nǹkan kékeré ni kí n jẹ́ iranṣẹ òun, láti gbé àwọn ẹ̀yà Jakọbu dìde, ati láti kó àwọn ọmọ Israẹli tí ó kù jọ. Ó ní òun óo fi mí ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè kí ìgbàlà òun lè dé òpin ayé. Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA, Olùràpadà Israẹli, ati Ẹni Mímọ́ rẹ̀, sọ, fún ẹni tí ayé ń gàn, tí àwọn orílẹ̀-èdè kórìíra, iranṣẹ àwọn aláṣẹ, ó ní, “Àwọn ọba yóo rí ọ, wọn óo dìde, àwọn ìjòyè yóo rí ọ, wọn óo sì dọ̀bálẹ̀. Nítorí OLUWA, tí ó jẹ́ olódodo, Ẹni Mímọ́ Israẹli, tí ó ti yàn ọ́.” OLUWA ní, “Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà mo dá ọ lóhùn, lọ́jọ́ ìgbàlà, mo ràn ọ́ lọ́wọ́. Mo ti pa ọ́ mọ́, mo sì ti fi ọ́ dá majẹmu pẹlu àwọn aráyé, láti fìdí ilẹ̀ náà múlẹ̀, láti pín ilẹ̀ tí ó ti di ahoro. Kí o máa sọ fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n pé, ‘Ẹ jáde,’ ati fún àwọn tí ó wà ninu òkùnkùn pé, ‘Ẹ farahàn.’ Wọn óo rí ohun jíjẹ ní gbogbo ọ̀nà, gbogbo orí òkè yóo sì jẹ́ ibùjẹ fún wọn. Ebi kò ní pa wọ́n, òùngbẹ kò sì ní gbẹ wọ́n, atẹ́gùn gbígbóná kò ní fẹ́ lù wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni oòrùn kò ní pa wọ́n, nítorí ẹni tí ó ṣàánú wọn ni yóo máa darí wọn, yóo sì mú wọn gba ẹ̀gbẹ́ omi tí ń ṣàn. “N óo sọ gbogbo òkè mi di ojú ọ̀nà, n óo kún gbogbo òpópó ọ̀nà mi. Wò ó! Òkèèrè ni èyí yóo ti wá, láti àríwá ati láti ìwọ̀ oòrùn, àní láti ilẹ̀ Sinimu.” Kí ọ̀run kọrin ayọ̀, kí ayé kún fún ayọ̀, ẹ̀yin òkè, ẹ máa kọrin, nítorí, OLUWA ti tu àwọn eniyan rẹ̀ ninu, yóo ṣàánú àwọn eniyan rẹ̀ tí ìyà ń jẹ. Sioni ń wí pé, “OLUWA ti kọ̀ mí sílẹ̀, Oluwa mi ti gbàgbé mi.” OLUWA dáhùn pé, “Ǹjẹ́ abiyamọ le gbàgbé ọmọ tí ń fún lọ́mú? Ṣé ó le má ṣàánú ọmọ bíbí inú rẹ̀? Bí àwọn wọnyi tilẹ̀ gbàgbé. Èmi kò ní gbàgbé rẹ. Wò ó! Mo ti fi gègé fín orúkọ rẹ sí àtẹ́lẹwọ́ mi, àwọn odi rẹ sì ńbẹ níwájú mi nígbà gbogbo. “Àwọn ọmọ rẹ tí ń pada bọ̀ kíákíá, àwọn olùparun rẹ yóo jáde kúrò ninu rẹ. Gbójú sókè, kí o wò yíká, gbogbo àwọn ọmọ rẹ péjọ, wọ́n tọ̀ ọ́ wá. OLUWA fi ara rẹ̀ búra pé, o óo gbé wọn wọ̀ bí nǹkan ọ̀ṣọ́ ara. O óo wọ̀ wọ́n bí ìgbà tí iyawo kó ohun ọ̀ṣọ́ wọ̀. “Dájúdájú ilẹ̀ rẹ tí ó ti di aṣálẹ̀, ati àwọn tí ó ti di ahoro, yóo kéré fún àwọn tí yóo máa gbé inú rẹ̀ tí ó bá yá, a óo sì lé àwọn tí ó pa ọ́ run jìnnà sí ọ. Àwọn ọmọ tí o bí ní àkókò ìgbèkùn rẹ yóo sọ ní etígbọ̀ọ́ rẹ pé, ‘Ibí yìí kéré jù fún wa, fún wa ní àyè sí i láti máa gbé.’ O óo bèèrè lọ́kàn ara rẹ nígbà náà pé, ‘Ta ni ó bí àwọn ọmọ wọnyi fún mi? Ṣebí àwọn ọmọ mi ti kú, mo ti yàgàn, mo sì lọ sí ìgbèkùn lóko ẹrú. Ta ni ó wá tọ́ àwọn wọnyi dàgbà? Ṣebí èmi nìkan ni mo ṣẹ́kù, níbo ni àwọn wọnyi ti wá?’ ” OLUWA Ọlọrun ní, “Wò ó, n óo gbé ọwọ́ mi sókè sí àwọn orílẹ̀-èdè. N óo gbé àsíá mi sókè sí àwọn eniyan, wọn óo gbé àwọn ọmọ rẹ ọkunrin mọ́ àyà wọn wọn óo sì gbé àwọn ọmọ rẹ obinrin sí èjìká. Àwọn ọba ni yóo máa tọ́jú rẹ bíi baba, àwọn ayaba yóo sì máa tọ́jú rẹ bí ìyá, ní ìdojúbolẹ̀ ni wọn óo máa tẹríba fún ọ, wọn óo sì máa pọ́n eruku ẹsẹ̀ rẹ lá. O óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA, ojú kò ní ti àwọn tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé mi.” Ǹjẹ́ a lè gba ìkógun lọ́wọ́ alágbára, tabi kí á gba òǹdè lọ́wọ́ òkúrorò eniyan? OLUWA ní: “Bí ó bá tilẹ̀ ṣeéṣe láti gba òǹdè lọ́wọ́ alágbára, tabi láti gba ìkógun lọ́wọ́ òkúrorò eniyan. N óo bá àwọn tí ó ń bá ọ jà jà, n óo sì gba àwọn ọmọ rẹ là. N óo mú kí àwọn tó ń ni ọ́ lára máa pa ara wọn jẹ: wọn óo máa mu ẹ̀jẹ̀ ara wọn, bí ẹni mu ọtí, gbogbo ayé yóo sì mọ̀ nígbà náà pé, èmi ni OLUWA, Olùgbàlà rẹ, Olùràpadà rẹ, Ọlọrun alágbára Jakọbu.” OLUWA ní: OLUWA ní: “Ìwé ìkọ̀sílẹ̀ tí mo fi kọ àwọn eniyan mi sílẹ̀ dà? Ta ni mo tà yín fún, tí mo jẹ lówó? Ẹ wò ó! Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín ni a ṣe tà yín, nítorí àìdára yín ni mo ṣe kọ̀ yín sílẹ̀. “Kí ló dé tí mo wá àwọn eniyan mi tí n kò rí ẹnìkan; mo pè, ẹnikẹ́ni kò dá mi lóhùn? Ṣé n kò lágbára tó láti rà wọ́n pada ni; àbí n kò lágbára láti gba ni là? Wò ó! Ìbáwí lásán ni mo fi gbẹ́ omi òkun, tí mo sì fi sọ odò tí ń ṣàn di aṣálẹ̀, omi wọn gbẹ, òùngbẹ gbẹ àwọn ẹja inú wọn pa, wọ́n kú, wọ́n sì ń rùn. Mo da òkùnkùn bo ojú ọ̀run bí aṣọ, mo ṣe aṣọ ọ̀fọ̀ ní ìbora fún wọn.” OLUWA Ọlọrun ti fi ọ̀rọ̀ ìmọ̀ sí mi lẹ́nu. Kí n lè mọ bí a tií gba àwọn tí ọkàn wọn rẹ̀wẹ̀sì níyànjú. Ojoojumọ ni ó ń ṣí mi létí láràárọ̀, kí n lè máa gbọ́rọ̀ bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́. OLUWA Ọlọrun ti ṣí mi létí, n kò sì ṣe oríkunkun, tabi kí n pada sẹ́yìn. Mo tẹ́ ẹ̀yìn sílẹ̀ fún àwọn tí ń nani lẹ́gba; mo sì kọ ẹ̀rẹ̀kẹ́ sí àwọn tí ń fa eniyan ní irùngbọ̀n tu. N kò fojú pamọ́ nítorí ẹ̀gàn, bẹ́ẹ̀ ni n kò gbójú sá fún itọ́ títu síni lójú. OLUWA Ọlọrun ń ràn mí lọ́wọ́, nítorí náà ojú kò tì mí; nítorí náà mo múra gírí, mo jẹ́ kí ojú mi le koko, mo sì mọ̀ pé ojú kò ní tì mí. Ẹni tí yóo dá mi láre wà nítòsí, ta ló fẹ́ bá mi jà? Ta ló fẹ́ fi ẹ̀sùn kàn mí? Kí olúwarẹ̀ súnmọ́ tòsí mi, kí á jọ kojú ara wa? Wò ó! OLUWA Ọlọrun ń ràn mí lọ́wọ́, ta ni yóo dá mi lẹ́bi? Gbogbo wọn ni yóo gbọ̀n dànù bí aṣọ, kòkòrò yóo sì jẹ wọ́n. Ta ló bẹ̀rù OLUWA ninu yín, tí ń gbọ́ràn sí iranṣẹ rẹ̀ lẹ́nu, tí ń rìn ninu òkùnkùn, tí kò ní ìmọ́lẹ̀, ṣugbọn sibẹ, tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, tí ó fẹ̀yìn ti Ọlọrun rẹ̀. Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń dáná, tí ẹ tan iná yí ara yín ká, ẹ máa rìn lọ ninu iná tí ẹ dá; ẹ máa la iná tí ẹ fi yí ara yín ká kọjá. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe fun yín. Ẹ óo wà ninu ìrora. “Ẹ gbọ́ ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sáré ìdáǹdè, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wá OLUWA, ẹ wo àpáta tí a mú lára rẹ̀, tí a fi gbẹ yín, ati kòtò ibi tí a ti wà yín jáde. Ẹ wo Abrahamu baba yín, ati Sara tí ó bi yín. Òun nìkan ni nígbà tí mo pè é, tí mo súre fún un, tí mo sì sọ ọ́ di ọpọlọpọ eniyan. “OLUWA yóo tu Sioni ninu, yóo tu gbogbo àwọn tí ó ṣòfò ninu rẹ̀ ninu; yóo sì sọ aṣálẹ̀ rẹ̀ dàbí Edẹni, ọgbà OLUWA. Ayọ̀ ati ìdùnnú ni yóo máa wà ninu rẹ̀, pẹlu orin ọpẹ́ ati orin ayọ̀. “Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin eniyan mi, ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, òfin kan yóo ti ọ̀dọ̀ mi jáde, ìdájọ́ òdodo mi yóo jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún àwọn eniyan. Ìdáǹdè mi súnmọ́ tòsí, ìgbàlà mi sì ti ń yọ bọ̀. Èmi ni n óo máa ṣe àkóso àwọn eniyan, àwọn erékùṣù yóo gbẹ́kẹ̀lé mi, ìrànlọ́wọ́ mi ni wọn yóo sì máa retí. Ẹ gbójú sókè, ẹ wo ojú ọ̀run, kí ẹ sì wo ayé ní ìsàlẹ̀. Ọ̀run yóo parẹ́ bí èéfín, ayé yóo gbó bí aṣọ, àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ yóo sì kú bíi kòkòrò; ṣugbọn títí lae ni ìgbàlà mi, ìdáǹdè mi kò sì ní lópin. “Ẹ̀yin tí ẹ mọ òdodo, ẹ gbọ́ ohùn mi, ẹ̀yin tí ẹ fi tọkàntọkàn gba òfin mi, ẹ má bẹ̀rù ẹ̀gàn àwọn eniyan; ẹ má sì jẹ́ kí yẹ̀yẹ́ wọn já a yín láyà. Ikán yóo jẹ wọ́n bí aṣọ, kòkòrò yóo jẹ wọ́n bí òwú; ṣugbọn ìdáǹdè mi yóo wà títí lae, ìgbàlà mi yóo sì wà láti ìran dé ìran.” Jí, jí! Dìde, OLUWA, jí pẹlu agbára; jí bí ìgbà àtijọ́, bí o ti ṣe sí ìran wa látijọ́. Ṣebí ìwọ ni o gé Rahabu wẹ́lẹwẹ̀lẹ, tí o fi idà gún diragoni? Àbí ìwọ kọ́ ni o mú kí omi òkun gbẹ, omi inú ọ̀gbun ńlá; tí o sọ ilẹ̀ òkun di ọ̀nà, kí àwọn tí o rà pada lè kọjá? Àwọn tí OLUWA rà pada yóo pada wá, pẹlu orin ni wọn óo pada wá sí Sioni. Adé ayọ̀ ni wọn óo dé sórí, wọn óo láyọ̀, inú wọn yóo dùn; ìbànújẹ́ ati ẹ̀dùn wọn yóo sì fò lọ. “Èmi fúnra mi ni mò ń tù ọ́ ninu, ta ni ọ́, tí o fi ń bẹ̀rù eniyan tí yóo kú? Ìwọ ń bẹ̀rù ọmọ eniyan tí a dá, bíi koríko. O gbàgbé OLUWA ẹlẹ́dàá rẹ, tí ó ta ojú ọ̀run bí aṣọ, tí ó fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀. O wá ń fi gbogbo ọjọ́ ayé bẹ̀rù ibinu àwọn aninilára, nítorí wọ́n múra tán láti pa ọ́ run? Ibinu àwọn aninilára kò ní dé ọ̀dọ̀ rẹ mọ́. Láìpẹ́, a óo tú àwọn tí a tẹ̀ lórí ba sílẹ̀. Wọn kò ní kú, wọn kò ní wọ inú isà òkú, wọn kò sì ní wá oúnjẹ tì. “Nítorí èmi ni OLUWA, Ọlọrun rẹ, ẹni tí ó rú òkun sókè, tí ìgbì rẹ̀ fi ń pariwo; OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ mi. Mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ọ lẹ́nu, mo ti pa ọ́ mọ́ lábẹ́ òjìji ọwọ́ mi. Èmi ni mo fi ojú ọ̀run sí ipò rẹ̀, tí mo fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, tí mo sì sọ fún ìlú Sioni pé, ‘Ẹ̀yin ni eniyan mi.’ ” Jí, jí! Dìde, ìwọ Jerusalẹmu. Ìwọ tí o ti rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ibinu OLUWA, ìwọ tí OLUWA ti fi ibinu jẹ níyà, tí ojú rẹ wá ń pòòyì. Kò sí ẹni tí yóo tọ́ ọ sọ́nà, ninu gbogbo àwọn ọmọ tí o ti bí, kò sí ẹni tí yóo fà ọ́ lọ́wọ́, ninu gbogbo ọmọ tí o tọ́ dàgbà. Àjálù meji ló dé bá ọ, ta ni yóo tù ọ́ ninu: Ìsọdahoro ati ìparun, ìyàn ati ogun, ta ni yóo tù ọ́ ninu? Àárẹ̀ mú àwọn ọmọ rẹ, wọ́n sùn káàkiri ní gbogbo òpópó, bí ìgalà tí ó bọ́ sinu àwọ̀n. Ibinu OLUWA rọ̀jò lé wọn lórí, àní ìbáwí Ọlọrun rẹ. Nítorí náà, ẹ̀yin tí à ń fi ìyà jẹ, ẹ gbọ́ èyí; ẹ̀yin tí ẹ ti yó láì tíì mu ọtí, Oluwa rẹ, àní OLUWA Ọlọrun rẹ, tí ń bẹ̀bẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan rẹ̀ ní, “Wò ó! Mo ti gba ife àmutagbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n lọ́wọ́ rẹ, O kò ní rí ibinu mi mọ́. Àwọn tí ń dá ọ lóró ni yóo rí ibinu mi, àwọn tí ó wí fún ọ pé, ‘Bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ kí á gba orí rẹ kọjá;’ tí wọ́n sọ ẹ̀yìn rẹ di ilẹ̀ẹ́lẹ̀, tí wọ́n sọ ọ́ di ojú ọ̀nà wọn, tí wọn óo máa gbà kọjá.” Jí, Sioni, jí! Gbé agbára rẹ wọ̀ bí aṣọ, gbé ẹwà rẹ wọ̀ bí ẹ̀wù, ìwọ Jerusalẹmu, ìlú mímọ́; nítorí àwọn aláìkọlà ati aláìmọ́, kò ní wọ inú rẹ mọ́. Dìde, gbọnranù kúrò ninu erùpẹ̀, ìwọ Jerusalẹmu tí ó wà ninu ìdè. Tú okùn tí a dè mọ́ ọ lọ́rùn kúrò, ìwọ Sioni tí ó wà ninu ìdè. Nítorí OLUWA ní, “Ọ̀fẹ́ ni a mu yín lẹ́rú, ọ̀fẹ́ náà sì ni a óo rà yín pada. Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn eniyan mi lọ ṣe àtìpó ní ilẹ̀ Ijipti, lẹ́yìn náà, àwọn ará Asiria pọ́n wọn lójú láì nídìí. Ṣugbọn nisinsinyii, kí ni mo rí yìí? Wọ́n mú àwọn eniyan mi lọ lọ́fẹ̀ẹ́, àwọn alákòóso wọn ń pẹ̀gàn, orúkọ mi wá di nǹkan yẹ̀yẹ́? Nítorí náà àwọn eniyan mi yóo mọ orúkọ mi, wọn óo sì mọ̀ ní ọjọ́ náà pé, èmi tí mò ń sọ̀rọ̀, èmi náà nìyí.” Ẹsẹ̀ ẹni tí ń mú ìyìn rere bọ̀ ti dára tó lórí òkè, ẹni tí ń kéde alaafia, tí ń mú ìyìn rere bọ̀, tí sì ń kéde ìgbàlà, tí ń wí fún Sioni pé, “Ọlọrun rẹ jọba.” Gbọ́, àwọn aṣọ́de rẹ gbóhùn sókè, gbogbo wọn jọ ń kọrin ayọ̀, nítorí wọ́n jọ fi ojú ara wọn rí i, tí OLUWA pada dé sí Sioni. Ẹ jọ máa kọrin pọ̀, gbogbo ilẹ̀ Jerusalẹmu tí a sọ di aṣálẹ̀, nítorí OLUWA yóo tu àwọn eniyan rẹ̀ ninu, yóo ra Jerusalẹmu pada. OLUWA yóo lo agbára mímọ́ rẹ̀, lójú àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo eniyan, títí dé òpin ayé, yóo sì rí ìgbàlà Ọlọrun wa. Ẹ jáde, ẹ jáde ẹ kúrò níbẹ̀, ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kan, ẹ jáde kúrò láàrin rẹ̀, kí ẹ sì wẹ ara yín mọ́, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ohun èlò OLUWA. Nítorí pé ẹ kò ní fi ìkánjú jáde, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní sáré jáde. Nítorí OLUWA yóo máa lọ níwájú yín, Ọlọrun Israẹli yóo sì wà lẹ́yìn yín. Wò ó! Iranṣẹ mi yóo ṣe àṣeyọrí a óo gbé e ga, a óo gbé e lékè; yóo sì di ẹni gíga, Ẹnu ti ya ọpọlọpọ eniyan nítorí rẹ̀. Wọ́n bà á lójú jẹ́ yánnayànna, tóbẹ́ẹ̀ tí ìrísí rẹ̀ kò fi jọ ti eniyan mọ́. Bẹ́ẹ̀ ni yóo di ohun ìyanu fún ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, kẹ́kẹ́ yóo pamọ́ àwọn ọba wọn lẹ́nu, nígbà tí wọ́n bá rí i, wọn óo rí ohun tí wọn kò gbọ́ rí nípa rẹ̀, òye ohun tí wọn kò mọ̀ rí yóo yé wọn. Ta ló lè gba ìyìn tí a rò gbọ́? Ta ni a ti fi agbára OLUWA hàn? Ó dàgbà níwájú rẹ̀ bí nǹkan ọ̀gbìn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ rúwé ati bíi gbòǹgbò láti inú ilẹ̀ gbígbẹ. Ìrísí rẹ̀ kò dára, ojú rẹ̀ kò fanimọ́ra, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ẹwà tí ìbá fi wu eniyan. Àwọn eniyan kẹ́gàn rẹ̀, wọ́n sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀; ẹni tí inú rẹ̀ bàjẹ́ tí ó sì mọ ìkáàánú ni. Ó dàbí ẹni tí àwọn eniyan ń wò ní àwòpajúdà. A kẹ́gàn rẹ̀, a kò sì kà á kún. Nítòótọ́, ó ti gbé ìkáàánú wa lọ, ó sì ti ru ìbànújẹ́ wa; sibẹsibẹ a kà á sí ẹni tí a nà, tí a sì jẹ níyà láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Ṣugbọn wọ́n ṣá a lọ́gbẹ́ nítorí àìdára wa, wọ́n pa á lára nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa; ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́ ni ó fún wa ní alaafia, nínà tí a nà án ni ó mú wa lára dá. Gbogbo wa ti ṣáko lọ bí aguntan, olukuluku wa yà sí ọ̀nà tirẹ̀, OLUWA sì ti kó ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo wa lé e lórí. Wọ́n ni í lára, wọ́n pọ́n ọn lójú, sibẹsibẹ kò lanu sọ̀rọ̀, wọ́n fà á lọ bí ọ̀dọ́ aguntan tí wọn ń lọ pa, ati bí aguntan tíí yadi níwájú àwọn tí ń rẹ́ irun rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò lanu sọ̀rọ̀. Wọ́n mú un lọ tipátipá, lẹ́yìn tí wọ́n ti dá a lẹ́jọ́, ta ni ninu ìran rẹ̀ tí ó ṣe akiyesi pé wọ́n ti pa á run lórí ilẹ̀ alààyè, ati pé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan mi, ni wọ́n ṣe nà án? Wọ́n tẹ́ ẹ sí ibojì, pẹlu àwọn eniyan burúkú, wọ́n sì sin ín pẹlu ọlọ́rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ṣe ẹnikẹ́ni níbi, kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn. Sibẹsibẹ, ó wu OLUWA láti pa á lára, ó sì fi í sinu ìbànújẹ́, nígbà tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀; yóo fojú rí ọmọ rẹ̀, ọjọ́ rẹ̀ yóo sì gùn. Ìfẹ́ OLUWA yóo ṣẹ lọ́wọ́ rẹ̀. Yóo rí èrè àníyàn ọkàn rẹ̀, yóo sì tẹ́ ẹ lọ́rùn; nípa ìmọ̀ rẹ̀ ni iranṣẹ mi, olódodo, yóo dá ọpọlọpọ eniyan láre, yóo sì ru ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Nítorí náà, n óo fún un ní ìpín, láàrin àwọn eniyan ńlá, yóo sì bá àwọn alágbára pín ìkógun, nítorí pé ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún ikú, wọ́n sì kà á mọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. Sibẹsibẹ ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọpọlọpọ eniyan, ó sì bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. Máa kọrin! Ìwọ àgàn tí kò bímọ. Máa kọrin sókè, ìwọ tí kò rọbí rí. Nítorí ọmọ ẹni tí ọkọ ṣátì pọ̀, ju ọmọ ẹni tí ń gbé ilé ọkọ lọ, OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. Fẹ ààyè àgọ́ rẹ sẹ́yìn, sì jẹ́ kí aṣọ tí ó ta sórí ibùgbé rẹ gbòòrò sí i, má ṣẹ́wọ́ kù. Na okùn àgọ́ rẹ kí ó gùn, kí o sì kan èèkàn rẹ̀ mọ́lẹ̀ kí ó lágbára. Nítorí o óo tàn kálẹ̀, sí apá ọ̀tún ati apá òsì, àwọn ọmọ rẹ yóo gba ìtẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè, wọn óo sì máa gbé àwọn ìlú tí ó ti di ahoro. Má bẹ̀rù nítorí ojú kò ní tì ọ́, má sì dààmú, nítorí a kì yóo dójú tì ọ́, nítorí o óo gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe rẹ, o kò sì ní ranti ẹ̀sín ìgbà tí o jẹ́ opó mọ́. Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ, OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀. Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ, Ọlọrun gbogbo ayé ni à ń pè é. Nítorí OLUWA ti pè ọ́, bí iyawo tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀, tí ọkàn rẹ̀ bàjẹ́, àní, bí iyawo àárọ̀ ẹni, tí a kọ̀ sílẹ̀; OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. Mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, ṣugbọn n óo kó ọ jọ pẹlu ọpọlọpọ àánú. Mo fojú mi pamọ́ fún ọ, fún ìgbà díẹ̀ nítorí inú mi ń ru sí ọ, ṣugbọn nítorí ìfẹ́ àìlópin mi, n óo ṣàánú fún ọ. Èmi OLUWA, Olùràpadà rẹ ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Bí ìgbà ayé Noa ni Ọ̀rọ̀ yìí rí sí mi: mo búra nígbà náà, pé omi Noa kò ní bo ayé mọ́lẹ̀ mọ́. Bẹ́ẹ̀ náà ni mo búra nisinsinyii, pé n kò ní bínú sí ọ mọ́, pé n kò ní bá ọ wí mọ́. Bí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ṣí kúrò, tí a sì ṣí àwọn òkè kéékèèké nídìí, ṣugbọn ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀, kò ní yẹ̀ lára rẹ, majẹmu alaafia mi tí mo bá ọ dá kò ní yẹ̀. Èmi OLUWA tí mo ṣàánú fún ọ ni mo sọ bẹ́ẹ̀. OLUWA ní: “Jerusalẹmu, ìwọ ẹni tí a pọ́n lójú, tí hílàhílo bá, tí a kò sì tù ninu, òkúta tí a fi oríṣìíríṣìí ọ̀dà kùn ni n óo fi kọ́ ọ, òkúta safire ni n óo sì fi ṣe ìpìlẹ̀ rẹ. Òkúta Agate ni n óo fi ṣe ṣóńṣó ilé rẹ, òkúta dídán ni n óo fi ṣe ẹnu ọ̀nà ibodè rẹ, àwọn òkúta olówó iyebíye ni n óo fi mọ odi rẹ. “Gbogbo àwọn ọmọ rẹ ọkunrin, ni OLUWA yóo kọ́ wọn yóo sì ṣe ọpọlọpọ àṣeyọrí. A óo fìdí rẹ múlẹ̀, ninu òdodo, o óo jìnnà sí ìnira, nítorí náà ẹ̀rù kò ní bà ọ́. O óo jìnnà sí ìpayà, nítorí kò ní súnmọ́ ọ. Bí ẹnìkan bá dojú ìjà kọ ọ́, kìí ṣe èmi ni mo rán an, ẹnikẹ́ni tó bá gbéjà kò ọ́, yóo ṣubú nítorí rẹ.” OLUWA ní, “Wò ó! Èmi ni mo dá alágbẹ̀dẹ, tí ó fi ẹwìrì fẹ́ná, tí ó sì rọ àwọn ohun ìjà, fún ìlò rẹ̀, èmi náà ni mo dá apanirun, pé kí ó máa panirun. Kò sí ohun ìjà tí a ṣe láti fi bá ọ jà tí yóo lágbára lórí rẹ. Gbogbo ẹni tí ó bá bá ọ rojọ́ nílé ẹjọ́, ni o óo jàre wọn. Èyí ni ìpín àwọn iranṣẹ OLUWA, ati ìdáláre wọn lọ́dọ̀ mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA ní, “Gbogbo ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ, ẹ máa bọ̀ níbi tí omi wà; bí ẹ kò tilẹ̀ lówó lọ́wọ́, ẹ wá ra oúnjẹ kí ẹ sì jẹ. Ẹ wá ra ọtí waini láì mú owó lọ́wọ́, kí ẹ sì ra omi wàrà, tí ẹnikẹ́ni kò díyelé. Kí ló dé tí ẹ̀ ń ná owó yín lórí ohun tí kì í ṣe oúnjẹ? Tí ẹ sì ń ṣe làálàá lórí ohun tí kì í tẹ́ni lọ́rùn? Ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi dáradára, kí ẹ sì jẹ ohun tí ó dára, ẹ jẹ oúnjẹ aládùn, kí inú yín ó dùn. “Ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi, ẹ gbọ́ ohun tí mò ń wí kí ẹ lè yè. N óo ba yín dá majẹmu ayérayé, ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ tí mo ṣe ìlérí fún Dafidi. Wò ó! Mo fi í ṣe olórí fún àwọn eniyan, olórí ati aláṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè. O óo pe àwọn orílẹ̀-èdè tí o kò mọ̀ rí, àwọn orílẹ̀-èdè tí kò mọ̀ ọ́ rí yóo sáré wá sọ́dọ̀ rẹ, nítorí OLUWA Ọlọrun rẹ, ati nítorí Ẹni Mímọ́ Israẹli, tí ó ṣe ọ́ lógo.” Ẹ wá OLUWA nígbà tí ẹ lè rí i, ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí. Kí eniyan burúkú fi ọ̀nà ibi rẹ̀ sílẹ̀, kí alaiṣododo kọ èrò burúkú rẹ̀ sílẹ̀, kí ó yipada sí OLUWA, kí OLUWA lè ṣàánú rẹ̀. Kí ó yipada sọ́dọ̀ Ọlọrun wa, nítorí Ọlọrun yóo dáríjì í lọpọlọpọ. OLUWA ní, “Nítorí èrò tèmi yàtọ̀ sí tiyín, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi yàtọ̀ sí tiyín, Bí ọ̀run ṣe ga ju ayé lọ, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín, tí èrò mi sì ga ju èrò yín. “Bí òjò ati yìnyín, tí ń rọ̀ láti ojú ọ̀run, tí wọn kì í pada sibẹ mọ́, ṣugbọn tí wọn ń bomi rin ilẹ̀, tí ń mú kí nǹkan hù jáde; kí àgbẹ̀ lè rí èso gbìn, kí eniyan sì rí oúnjẹ jẹ. Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ tó ń jáde lẹ́nu mi yóo rí, kò ní pada sí ọ̀dọ̀ mi lọ́wọ́ òfo, ṣugbọn yóo ṣe ohun tí mo fẹ́ kí ó ṣe, yóo sì ṣe é ní àṣeyọrí. “Nítorí tayọ̀tayọ̀ ni ẹ óo fi máa jáde ní Babiloni, alaafia ni wọ́n óo fi máa sìn yín sọ́nà, òkè ńlá ati kéékèèké yóo máa kọrin níwájú yín. Gbogbo igi inú igbó yóo sì máa pàtẹ́wọ́, igi Sipirẹsi ni yóo máa hù dípò igi ẹlẹ́gùn-ún, igi Mitili ni yóo sì máa hù dípò ẹ̀gún ọ̀gàn, yóo jẹ́ àmì ìrántí fún OLUWA, ati àpẹẹrẹ ayérayé tí a kò ní parẹ́.” OLUWA ní: “Ẹ máa dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́, kí ẹ sì máa ṣe òdodo; nítorí ìgbàlà mi yóo dé láìpẹ́, ẹ óo sì rí ìdáǹdè mi. Ayọ̀ ń bẹ fún gbogbo ẹni tí ó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ati fún ẹni tí ó bá ń tẹ̀lé e, tí ó ń ṣọ́ra, tí kò rú òfin ọjọ́ ìsinmi, tí kò sì fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe nǹkan burúkú.” Kí àjèjì tí ó faramọ́ OLUWA má sọ pé, “Dájúdájú OLUWA yóo yà mí kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀.” Kí ìwẹ̀fà má sì sọ pé, “Wò ó! Mo dàbí igi gbígbẹ.” Nítorí OLUWA ní, “Bí ìwẹ̀fà kan bá pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, tí ó bá ṣe ohun tí mo fẹ́, tí ó sì di majẹmu mi mú gbọningbọnin, n óo fún wọn ní ipò láàrin àgbàlá mi, ati ìrántí tí ó dára, ju ọmọkunrin ati ọmọbinrin lọ. Orúkọ tí kò ní parẹ́ laelae, ni n óo fún wọn. “Àwọn àjèjì tí ó bá darapọ̀ mọ́ OLUWA, tí wọn ń sìn ín, tí wọn fẹ́ràn rẹ̀, tí wọn sì ń ṣe iranṣẹ rẹ̀, gbogbo àwọn tí ó bá pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, tí kò sọ ọ́ di ohun ìríra, tí ó sì di majẹmu mi mú gbọningbọnin, n óo mú wọn wá sí orí òkè mímọ́ mi, n óo jẹ́ kí inú wọn máa dùn ninu ilé adura mi. Ọrẹ sísun ati ẹbọ wọn, yóo jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lórí pẹpẹ mi; nítorí ilé adura fún gbogbo eniyan, ni a óo máa pe ilé mi.” OLUWA Ọlọrun tí ń kó àwọn tí ogun túká ní Israẹli jọ sọ pé, “N óo tún kó àwọn mìíràn jọ, kún àwọn tí mo ti kọ́ kó jọ.” Gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè láti òkèèrè, ẹ máa bọ̀, gbogbo yín ẹ máa bọ̀ bí ẹranko inú ìgbẹ́, ẹ wá jẹ àjẹrun. Afọ́jú ni àwọn aṣọ́de Israẹli gbogbo wọn kò mọ nǹkankan. Ajá tí ó yadi ni wọ́n, wọn kò lè gbó; oorun ni wọ́n fẹ́ràn. Wọn á dùbúlẹ̀, wọn á máa lá àlá. Wọ̀bìà ni wọ́n, alájẹkì, wọn kì í yó. Àwọn olùdarí wọn pàápàá kò mọ nǹkankan. Gbogbo wọn ti tẹ̀ sí ọ̀nà ara wọn, olukuluku wọn ń wá èrè fún ara rẹ̀. Wọn á máa sọ pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á mu waini, ẹ jẹ́ kí á mu ọtí líle ní àmuyó, bí òní ṣe rí ni ọ̀la yóo rí, yóo dùn tayọ.” Olódodo ń ṣègbé, kò sí ẹni tí ó fi ọkàn sí i. A mú àwọn olótìítọ́ kúrò, kò sì sí ẹni tí ó yé, pé à ń yọ olódodo kúrò ninu ìdààmú ni. Àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà òtítọ́, wọn óo wà ní alaafia, wọn óo máa sinmi lórí ibùsùn wọn. Ẹ̀yin ọmọ oṣó wọnyi, ẹ súnmọ́bí fún ìdájọ́, ẹ̀yin ọmọ alágbèrè ati panṣaga. Ta ni ẹ̀ ń fi ṣe ẹlẹ́yà? Ta ni ẹ̀ ń ya ẹnu ní ìyàkuyà sí tí ẹ yọ ṣùtì sí? Ṣebí ọmọ ẹ̀ṣẹ̀ ni yín irú ọmọ ẹ̀tàn; ẹ̀yin tí ẹ kún fún ìṣekúṣe lábẹ́ igi Oaku, ati lábẹ́ gbogbo igi eléwé tútù. Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń pa àwọn ọmọ yín láàrin àfonífojì, ati ní abẹ́ àpáta? Àwọn oriṣa láàrin àwọn òkúta ọ̀bọ̀rọ́, ninu àfonífojì, àwọn ni ẹ̀ ń sìn, àwọn ni ò ń da ẹbọ ohun mímu lé lórí, àwọn ni ò ń fi nǹkan jíjẹ rúbọ sí. Ṣé àwọn nǹkan wọnyi ni yóo mú kí inú mi yọ́? Lórí òkè gíga fíofío, ni o lọ tẹ́ ibùsùn rẹ sí níbẹ̀ ni o tí ń lọ rú ẹbọ. O gbé ère oriṣa kalẹ̀ sí ẹ̀yìn ìlẹ̀kùn ati ẹ̀yìn òpó ìlẹ̀kùn. O kọ̀ mí sílẹ̀, o bọ́ sórí ibùsùn, o tẹ́ ibùsùn tí ó fẹ̀. O wá bá àwọn tí ó wù ọ́ da ọ̀rọ̀ pọ̀, ẹ̀ ń bá ara yín lòpọ̀. O gbọ̀nà, o lọ gbé òróró fún oriṣa Moleki, o kó ọpọlọpọ turari lọ, o rán àwọn ikọ̀ lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, o sì ranṣẹ lọ sinu isà òkú pẹlu. Àárẹ̀ mú ọ nítorí ìrìn àjò rẹ jìnnà, sibẹsibẹ o kò sọ fún ara rẹ pé, “Asán ni ìrìn àjò yìí.” Ò ń wá agbára kún agbára, nítorí náà àárẹ̀ kò mú ọ. Ta ni ń já ọ láyà, tí ẹ̀rù rẹ̀ bà ọ́, tí o fi purọ́; tí o kò ranti mi, tí o kò sì ronú nípa mi? Ṣé nítorí mo ti dákẹ́ fún ìgbà pípẹ́, ni o kò fi bẹ̀rù mi? N óo sọ nípa òdodo rẹ ati iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, ṣugbọn wọn kò ní lè ràn ọ́ lọ́wọ́. Nígbà tí o bá kígbe, kí àwọn ère tí o kó jọ gbà ọ́. Atẹ́gùn lásán ni yóo gbé gbogbo wọn lọ Afẹ́fẹ́ ni yóo fẹ́ wọn lọ. Ṣugbọn ẹni tí ó bá sá di mí, ni yóo ni ilẹ̀ náà, òun ni yóo sì jogún òkè mímọ́ mi. OLUWA ní, “Ẹ la ọ̀nà, ẹ la ọ̀nà, ẹ tún ọ̀nà ṣe, ẹ mú gbogbo ohun ìkọsẹ̀ kúrò lọ́nà àwọn eniyan mi.” Nítorí Ẹni Gíga, tí ó ga jùlọ, ẹni tí ń gbé ninu ayérayé, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mímọ́: òun ni ó ní, “Ibi gíga ati mímọ́ ni mò ń gbé lóòótọ́, ṣugbọn mo wà pẹlu àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn ati àwọn onírẹ̀lẹ̀. Láti sọ ọkàn wọn jí. Nítorí n kò ní máa jà títí ayé, tabi kí n máa bínú nígbà gbogbo: nítorí láti ọ̀dọ̀ mi ni ẹ̀mí ti ń jáde, Èmi ni mo dá èémí ìyè. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ojúkòkòrò rẹ̀, inú bí mi, mo jẹ ẹ́ níyà, mo fojú pamọ́, inú sì bí mi; sibẹ ó túbọ̀ ń ṣìnà sí i ni, ó ń ṣe tinú rẹ̀. Mo ti rí bí ó ti ń ṣe, ṣugbọn n óo ṣì wò ó sàn; n óo máa darí rẹ̀, n óo tù ú ninu, n óo sì fún àwọn tí ó bá ń ṣọ̀fọ̀ ní Israẹli ní orin ayọ̀. Alaafia ni, alaafia ni fún àwọn tí ó wà ní òkèèrè, ati àwọn tí ó wà nítòsí; n óo sì wò wọ́n sàn. Ṣugbọn àwọn eniyan burúkú dàbí ríru omi òkun, nítorí òkun kò lè sinmi, omi rẹ̀ a sì máa rú pàǹtí ati ẹrẹ̀ sókè. Kò sí alaafia fún àwọn eniyan burúkú.” Ọlọrun mi ló sọ bẹ́ẹ̀. “Kígbe sókè, má dákẹ́, ké sókè bíi fèrè ogun, sọ ìrékọjá àwọn eniyan mi fún wọn ní àsọyé, sọ ẹ̀ṣẹ̀ ilé Jakọbu fún wọn. Nítòótọ́ ni wọ́n ń wá mi lojoojumọ, wọ́n sì fẹ́ mọ ìlànà mi, wọ́n ṣe bí orílẹ̀-èdè tí ó mọ òdodo, tí kò kọ òfin Ọlọrun wọn sílẹ̀. Wọ́n ń bèèrè ìdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ mi, wọ́n ní ìfẹ́ ati súnmọ́ Ọlọrun.” Wọ́n ń bèèrè pé, “Kí ló dé tí à ń gbààwẹ̀, ṣugbọn tí OLUWA kò rí wa? Tí à ń fìyà jẹ ara wa, ṣugbọn tí kò náání wa?” OLUWA wí pé, “Ìdí rẹ̀ ni pé, nígbà tí ẹ bá ń gbààwẹ̀, ẹ̀ máa ṣe ìfẹ́ ọkàn yín. Ẹ̀ sì máa ni gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ yín lára. Ẹ̀ ń kún fún ìjà ati asọ̀ ní àkókò ààwẹ̀ yín, ẹ̀ ń lu ara yín ní ìlù ìkà. Irú ààwẹ̀ tí ẹ̀ ń gbà yìí kò ní jẹ́ kí Ọlọrun gbọ́ ohùn yín lọ́run. Ṣé irú ààwẹ̀ tí mo yàn nìyí, ọjọ́ tí eniyan yóo rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ lásán? Ṣé kí eniyan lè doríkodò bíi koríko etí odò nìkan ni? Tabi kí ó lè jókòó lórí aṣọ ọ̀fọ̀ ati eérú nìkan? Ṣé èyí ni ẹ̀ ń pè ní ààwẹ̀, ati ọjọ́ tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ OLUWA? “Ṣebí irú ààwẹ̀ tí mo yàn ni pé: kí á tú ìdè ìwà burúkú, kí á yọ irin tí a fi di igi àjàgà; kí á dá àwọn tí ìyà ń jẹ sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́, kí á já gbogbo àjàgà? Àní kí ẹ fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ, kí ẹ mú àwọn òtòṣì aláìnílé wá sinu ilé yín, bí ẹ bá rí ẹnikẹ́ni ní ìhòòhò, kí ẹ fi aṣọ bò ó, kí ẹ má sì fojú pamọ́ fún ẹni tí ó jẹ́ ẹbí yín. “Nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ yín yóo tàn bí ìgbà tí ilẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ́, ara yín yóo sì tètè yá. Òdodo yín yóo máa tàn níwájú yín. Ògo mi yóo ṣe ààbò lẹ́yìn yín. Ẹ óo ké pè mí nígbà náà, n óo sì da yín lóhùn. Ẹ óo kígbe pè mí, n óo sì dáhùn pé, ‘Èmi nìyí.’ “Bí ẹ bá mú àjàgà kúrò láàrin yín, tí ẹ kò fi ìka gún ara yín nímú mọ́, tí ẹ kò sì sọ ọ̀rọ̀ ibi mọ́. Bí ẹ bá ṣe làálàá láti fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ, tí ẹ sì wá ọ̀nà ìtẹ́lọ́rùn fún ẹni tí ìyà ń jẹ, ìmọ́lẹ̀ yín yóo tàn ninu òkùnkùn, òkùnkùn biribiri yín yóo dàbí ọ̀sán. N óo máa tọ yín sọ́nà nígbà gbogbo, n óo fi nǹkan rere tẹ yín lọ́rùn; n óo mú kí egungun yín ó le, ẹ óo sì dàbí ọgbà tí à ń bomi rin, ati bí orísun omi, tí omi rẹ̀ kì í gbẹ. Ẹ óo tún odi yín tí ó ti wó lulẹ̀ mọ, ẹ óo sì gbé àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ àtijọ́ dìde. Àwọn eniyan yóo máa pè yín ní alátùn-únṣe ibi tí odi ti wó, alátùn-únṣe òpópónà àdúgbò fún gbígbé. “Bí ẹ bá dẹ́kun láti máa ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́, tí ẹ kò sì máa ṣe ìfẹ́ inú yín lọ́jọ́ mímọ́ mi; bí ẹ bá pe ọjọ́ ìsinmi ní ọjọ́ ìdùnnú, tí ẹ pe ọjọ́ mímọ́ OLUWA ní ọjọ́ ológo; bí ẹ bá yẹ́ ẹ sí, tí ẹ kò yà sí ọ̀nà tiyín, tí ẹ kò máa ṣe ìfẹ́ inú ara yín, tabi kí ẹ máa sọ̀rọ̀ àhesọ; nígbà náà ni inú yín yóo máa dùn láti sin èmi OLUWA, n óo gbe yín gun orí òkè ilẹ̀ ayé, n óo sì mu yín jogún Jakọbu, baba ńlá yín. Èmi OLUWA ni ó sọ bẹ́ẹ̀.” Wò ó! Agbára OLUWA kò dínkù, tí ó fi lè gbani là, etí rẹ̀ kò di, tí kò fi ní gbọ́. Ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ yín ni ó fa ìyapa láàrin ẹ̀yin ati Ọlọrun yín, àìdára yín ni ó mú kí ó fojú pamọ́ fun yín, tí kò fi gbọ́ ẹ̀bẹ̀ yín. Ìpànìyàn ti sọ ọwọ́ yín di aláìmọ́, ọwọ́ yín kún fún ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀ ń purọ́, ẹ sì ń fi ẹnu yín sọ ọ̀rọ̀ burúkú. Kò sí ẹni tí ó ń pe ẹjọ́ àre, kò sì sí ẹni tí ó ń rojọ́ òdodo. Ẹjọ́ òfo ni ẹ gbójú lé. Ẹ kún fún irọ́ pípa, ìkà ń bẹ ninu yín, iṣẹ́ burúkú sì ń bẹ lọ́wọ́ yín. Ẹ̀ ń bá paramọ́lẹ̀ pa ẹyin rẹ̀, ẹ sì ń ran òwú aláǹtakùn, ẹni tí ó bá jẹ ninu ẹyin yín yóo kú. Bí ẹnìkan bá fọ́ ọ̀kan ninu ẹyin yín, ejò paramọ́lẹ̀ ni yóo jáde sí i. Òwú aláǹtakùn yín kò lè di aṣọ, eniyan kò ní fi iṣẹ́ ọwọ́ yín bora. Iṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ni iṣẹ́ yín, ìwà ipá sì ń bẹ lọ́wọ́ yín. Ẹsẹ̀ yín yá sí ọ̀nà ibi, ẹ sì yára sí àtipa aláìṣẹ̀. Èrò ẹ̀ṣẹ̀ ni èrò ọkàn yín. Ọ̀nà yín kún fún ìsọdahoro ati ìparun. Ẹ kò mọ ọ̀nà alaafia, kò sí ìdájọ́ òdodo ní ọ̀nà yín. Ẹ ti mú kí ọ̀nà yín wọ́, ẹni tó bá ba yín rìn kò ní ní alaafia. Àwọn eniyan bá dáhùn pé, “Nítorí náà ni ìdájọ́ òtítọ́ fi jìnnà sí wa, tí òdodo kò sì fi dé ọ̀dọ̀ wà. Ìmọ́lẹ̀ ni à ń retí, ṣugbọn òkùnkùn ló ṣú, ìtànṣán oòrùn ni à ń retí, ṣugbọn ìkùukùu ni ó bolẹ̀. À ń táràrà lára ògiri bí afọ́jú, à ń táràrà bí ẹni tí kò lójú. À ń kọsẹ̀ lọ́sàn-án gangan, bí ẹni tí ó jáde ní àfẹ̀mọ́júmọ́ a dàbí òkú láàrin àwọn alágbára. Gbogbo wa ń bú bí ẹranko beari, a sì ń ké igbe ẹ̀dùn bí àdàbà. À ń retí ìdájọ́ òdodo, ṣugbọn kò sí; à ń retí ìgbàlà, ṣugbọn ó jìnnà sí wa. “Nítorí àìdára wa pọ̀ níwájú rẹ, ẹ̀ṣẹ̀ wa sì ń jẹ́rìí lòdì sí wa; nítorí àwọn àìdára wa wà pẹlu wa, a sì mọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa: A ń kọjá ààyè wa, à ń sẹ́ OLUWA, a sì ń yipada kúrò ní ọ̀nà Ọlọrun wa. Ọ̀rọ̀ ìninilára ati ọ̀tẹ̀ ni à ń sọ, èrò ẹ̀tàn ní ń bẹ lọ́kàn wa, ọ̀rọ̀ èké sì ní ń jáde lẹ́nu wa. A fi ọwọ́ rọ́ ẹjọ́ ẹ̀tọ́ sẹ́yìn, òdodo sì takété. Òtítọ́ ti ṣubú ní gbangba ìdájọ́, ìdúróṣinṣin kò rọ́nà wọlé. Òtítọ́ di ohun àwátì, ẹni tí ó yàgò fún iṣẹ́ ibi fi ara rẹ̀ fún ayé mú.” OLUWA rí i pé kò sí ìdájọ́ òdodo, ó sì bà á lọ́kàn jẹ́, Ó rí i pé kò sí ẹnìkan tí yóo ṣe onílàjà, ẹnu sì yà á, pé kò sí ẹnìkankan. Ó bá fi ọwọ́ rẹ̀ ṣẹgun fún ara rẹ̀, òdodo rẹ̀ sì gbé e dúró. Ó gbé òdodo wọ̀ bí ìgbàyà, ó fi àṣíborí ìgbàlà borí. Ó gbé ẹ̀san wọ̀ bí ẹ̀wù, ó fi bora bí aṣọ. Yóo san ẹ̀san fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn, yóo bínú sí àwọn tí wọ́n lòdì sí i, yóo sì san ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá rẹ̀, ati àwọn tí ń gbé erékùṣù. Wọn óo bẹ̀rù orúkọ OLUWA láti ìwọ̀ oòrùn, wọn óo bẹ̀rù ògo rẹ̀ láti ìlà oòrùn; nítorí yóo wá bí ìkún omi, tí ẹ̀fúùfù láti ọ̀dọ̀ OLUWA ń taari. OLUWA ní, “N óo wá sí Sioni bí Olùràpadà, n óo wá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Jakọbu, tí wọ́n yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀. “Majẹmu tí Èmi bá wọn dá nìyí: Ẹ̀mí mi tí mo fi le yín lórí, ati ọ̀rọ̀ mi tí mo fi si yín lẹ́nu, kò gbọdọ̀ kúrò lẹ́nu yín, ati lẹ́nu àwọn ọmọ rẹ, ati lẹ́nu arọmọdọmọ yín, láti àkókò yìí lọ ati títí laelae. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” Dìde, tan ìmọ́lẹ̀; nítorí ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé, ògo OLUWA sì ti tàn sára rẹ. Nítorí òkùnkùn yóo bo ayé mọ́lẹ̀, òkùnkùn biribiri yóo sì bo àwọn orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀, ṣugbọn ìmọ́lẹ̀ OLUWA yóo tàn sára rẹ, ògo OLUWA yóo sì hàn lára rẹ. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo wá sinu ìmọ́lẹ̀ rẹ, àwọn ọba yóo sì wá sinu ìmọ́lẹ̀ rẹ tí ń tàn. Gbé ojú sókè kí o wò yíká, gbogbo wọn kó ara wọn jọ, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ rẹ; àwọn ọmọ rẹ ọkunrin yóo wá láti òkèèrè, a óo sì gbé àwọn ọmọ rẹ obinrin lé apá wá. Nígbà tí o bá rí wọn, inú rẹ yóo dùn, ara rẹ óo yá gágá. Ọkàn rẹ yóo kún fún ayọ̀, nítorí pé a óo gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọrọ̀ inú òkun wá sọ́dọ̀ rẹ. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo kó ọrọ̀ wọn wá fún ọ. Ogunlọ́gọ̀ ràkúnmí yóo yí ọ ká, àwọn ọmọ ràkúnmí Midiani ati Efa. Gbogbo àwọn tí wọn wà ní Ṣeba yóo wá, wọn óo mú wúrà ati turari wá; wọn óo sì máa pòkìkí OLUWA. Gbogbo ẹran ọ̀sìn Kedari ni wọ́n óo kó wá fún ọ, wọn óo kó àgbò Nebaiotu wá ta ọ́ lọ́rẹ. Wọn óo jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lórí pẹpẹ mi, ilé mi lógo, ṣugbọn n óo tún ṣe é lógo sí i. Ta ni àwọn wọnyi tí ń fò lọ bí ìkùukùu? Bí ìgbà tí àwọn àdàbà bá ń fò lọ sí ibi ìtẹ́ wọn? Nítorí àwọn erékùṣù yóo dúró dè mí, ọkọ̀ ojú omi Taṣiṣi ni yóo ṣiwaju wọn óo kó àwọn ọmọkunrin rẹ wá láti ilẹ̀ òkèèrè, wọn óo kó wúrà ati fadaka wá pẹlu wọn; nítorí orúkọ OLUWA Ọlọrun rẹ, ati Ẹni Mímọ́ Israẹli, nítorí ó ti ṣe ọ́ lógo. OLUWA ní, “Àwọn àjèjì ni yóo máa tún odi rẹ mọ, àwọn ọba wọn yóo sì máa ṣe iranṣẹ fún ọ; nítorí pé inú ló bí mi ni mo fi nà ọ́. Ṣugbọn nítorí ojurere mi ni mo fi ṣàánú fún ọ. Ṣíṣí ni ìlẹ̀kùn rẹ yóo máa wà nígbà gbogbo, a kò ní tì wọ́n tọ̀sán-tòru; kí àwọn eniyan lè máa kó ọrọ̀ orílẹ̀-èdè wá fún ọ, pẹlu àwọn ọba wọn tí wọn yóo máa tì siwaju. Orílẹ̀-èdè tabi ilẹ̀ ọba tí kò bá sìn ọ́ yóo parun, wọn óo di àwópalẹ̀ patapata. “Ògo Lẹbanoni yóo wá sí ọ̀dọ̀ rẹ: igi sipirẹsi, igi firi, ati igi pine; láti bukun ẹwà ilé mímọ́ mi, n óo sì ṣe ibi ìtìsẹ̀ mi lógo. Àwọn ọmọ àwọn tí ń ni ọ́ lára yóo wá, wọn óo tẹríba fún ọ; gbogbo àwọn tí ń kẹ́gàn rẹ, yóo wá tẹríba lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ; wọn óo pè ọ́ ní ìlú OLÚWA, Sioni ti Ẹni Mímọ́ Israẹli. “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kọ̀ ọ́, wọ́n sì kórìíra rẹ, tí kò sí ẹni tí ń gba ààrin rẹ̀ kọjá mọ́, n óo sọ ọ́ di àmúyangàn títí lae; àní, ohun ayọ̀ láti ìrandíran. O óo mu wàrà àwọn orílẹ̀-èdè, o óo mu wàrà àwọn ọba. O óo sì mọ̀ pé èmi OLUWA, ni olùgbàlà rẹ, ati Olùràpadà rẹ, Ẹni Ńlá Jakọbu. “Dípò bàbà, wúrà ni n óo mú wá. Dípò irin, fadaka ni n óo mú wá. Dípò igi, bàbà ni n óo mú wá. Dípò òkúta, irin ni n óo mú wá. N óo mú kí àwọn alabojuto yín wà ní alaafia, àwọn akóniṣiṣẹ́ yín yóo sì máa ṣe òdodo. Kò tún ní sí ìró ìdàrúdàpọ̀ ní ilẹ̀ rẹ mọ́, kò sì ní sí ìdágìrì ati ìparun ní ibodè rẹ, o óo máa pe odi rẹ ní ìgbàlà, o óo sì máa pe ẹnubodè rẹ ní ìyìn. “Kì í ṣe oòrùn ni yóo máa tan ìmọ́lẹ̀ fún ọ mọ́ ní ọ̀sán, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe òṣùpá ni yóo máa tan ìmọ́lẹ̀ fún ọ mọ́ ní òru: OLUWA ni yóo máa jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé fún ọ, Ọlọrun rẹ yóo sì jẹ́ ògo rẹ. Oòrùn rẹ kò ní wọ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni òṣùpá rẹ kò ní wọ òkùnkùn. Nítorí OLUWA ni yóo jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé fún ọ, ọjọ́ ọ̀fọ̀ rẹ yóo sì dópin. Gbogbo àwọn eniyan rẹ yóo jẹ́ olódodo, àwọn ni yóo jogún ilẹ̀ náà títí lae. Àwọn ni ẹ̀ka igi tí mo gbìn, iṣẹ́ ọwọ́ mi, kí á baà lè yìn mí lógo. Ìdílé tí ó rẹ̀yìn jùlọ yóo di orílẹ̀-èdè, èyí tí ó sì kéré jùlọ yóo di orílẹ̀-èdè ńlá, Èmi ni OLUWA, kíákíá ni n óo ṣe é nígbà tí àkókò rẹ̀ bá tó.” Ẹ̀mí OLUWA, Ọlọrun tí bà lé mi, nítorí ó ti fi àmì òróró yàn mí, láti mú ìròyìn ayọ̀ wá fún àwọn tí a ni lára. Ó rán mi pé kí n máa tu àwọn tí ó ní ìbànújẹ́ ninu, kí n máa kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn tí ó wà ní ìgbèkùn, kí n sì máa ṣí ìlẹ̀kùn ọgbà ẹ̀wọ̀n sílẹ̀ fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n. Ó ní kí n máa kéde ọdún ojurere OLUWA, ati ọjọ́ ẹ̀san Ọlọrun wa; kí n sì máa tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ninu. Ó ní kí n máa fún àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ní Sioni, ní inú dídùn dípò ìkáàánú, kí n fún wọn ní ayọ̀ dípò ìbànújẹ́, kí n jẹ́ kí wọn máa kọrin ìyìn dípò ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn, kí á lè máa pè wọ́n ní igi òdodo, tí OLUWA gbìn, kí á lè máa yìn ín lógo. Wọn óo tún àlàpà ahoro àtijọ́ kọ́, wọn óo tún gbogbo ilé tí ó ti wó lulẹ̀ kọ́, wọn óo sì tún ìlú tí a ti parun láti ọdún gbọọrọ kọ́. Àwọn àjèjì ni yóo máa ba yín bọ́ agbo ẹran yín, àwọn ni yóo sì máa ṣe alágbàṣe ninu ọgbà àjàrà yín; ṣugbọn a óo máa pe ẹ̀yin ní alufaa OLUWA, àwọn eniyan yóo sì máa sọ̀rọ̀ yín bí iranṣẹ Ọlọrun wa. Ẹ̀yin ni ẹ óo máa jẹ ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, ọrọ̀ wọn ni ẹ óo sì máa fi ṣògo. Dípò ìtìjú ìpín tiyín yóo jẹ́ meji, dípò àbùkù ẹ óo láyọ̀ ninu ìpín tí ó kàn yín. Ìlọ́po meji ni ìpín yín yóo jẹ́ ninu ilẹ̀ yín, ayọ̀ ayérayé yóo sì jẹ́ tiyín. OLUWA ní, “Nítorí pé mo fẹ́ ẹ̀tọ́, mo sì kórìíra ìfipá jalè ati ohun tí kò tọ́. Dájúdájú n óo san ẹ̀san fún wọn, n óo sì bá wọn dá majẹmu ayérayé. Àwọn ọmọ wọn yóo dá yàtọ̀ láàrin orílẹ̀-èdè, a óo dá arọmọdọmọ wọn mọ̀ láàrin àwọn eniyan, gbogbo àwọn tí ó bá rí wọn, yóo gbà pé èmi OLUWA ti bukun wọn.” N óo máa yọ̀ ninu OLUWA, ọkàn mi yóo kún fún ayọ̀ sí Ọlọrun mi. Nítorí ó ti fi ìgbàlà wọ̀ mí bí ẹ̀wù, ó sì ti fi òdodo bòmí lára bí aṣọ; bí ọkọ iyawo tí ó ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́, ati bí iyawo tí ó ṣe ọ̀ṣọ́ jìngbìnnì. Bí ilẹ̀ tíí mú kí ewéko hù jáde, tí ọgbà sì ń mú kí ohun tí a gbìn sinu rẹ̀ hù, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA Ọlọrun yóo mú kí òdodo ati orin ìyìn yọ jáde níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè. Nítorí Sioni, ń kò ní dákẹ́, nítorí Jerusalẹmu, ń kò ní sinmi, títí ìdáláre rẹ̀ yóo fi yọ bí ìmọ́lẹ̀, tí ìgbàlà rẹ̀ yóo sì tàn bí àtùpà. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo rí ìdáláre rẹ, gbogbo ọba ni yóo rí ògo rẹ; orúkọ tuntun, tí OLUWA fúnra rẹ̀ yóo sọ ọ́, ni a óo máa pè ọ́. O óo jẹ́ adé ẹwà lọ́wọ́ OLUWA, ati fìlà oyè lọ́wọ́ Ọlọrun rẹ. A kò ní pè ọ́ ní “Ẹni-tí-a-kọ̀-sílẹ̀” mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní pe ilẹ̀ rẹ ní “Ahoro” mọ́, “Ẹni-OLUWA-fẹ́” ni a óo máa pè ọ́, a óo máa pe ilẹ̀ rẹ ní “Ẹni-a-gbé-níyàwó.” Nítorí pé OLUWA nífẹ̀ẹ́ rẹ, ilẹ̀ rẹ yóo sì dàbí iyawo lójú rẹ̀. Bí ọdọmọkunrin tií nífẹ̀ẹ́ wundia, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkunrin rẹ yóo nífẹ̀ẹ́ rẹ. Bí inú ọkọ iyawo tuntun tíí dùn nítorí iyawo rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọrun rẹ yóo dùn nítorí rẹ. Jerusalẹmu, mo ti fi àwọn aṣọ́de sí orí odi rẹ; lojoojumọ, tọ̀sán-tòru, wọn kò gbọdọ̀ panumọ́. Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń rán OLUWA létí, ẹ má dákẹ́. Ẹ má jẹ́ kí ó sinmi, títí yóo fi fi ìdí Jerusalẹmu múlẹ̀, títí yóo fi sọ ọ́ di ìlú ìyìn láàrin gbogbo ayé. OLUWA ti fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ búra, ó ti fi agbára rẹ̀ jẹ́ ẹ̀jẹ́, pé òun kò ní fi ọkà oko rẹ, ṣe oúnjẹ fún àwọn ọ̀tá rẹ mọ́; àwọn àjèjì kò sì ní mu ọtí waini rẹ, tí o ṣe wahala lé lórí mọ́. Ṣugbọn àwọn tí ó bá gbin ọkà, ni yóo máa jẹ ẹ́, wọn óo sì máa fìyìn fún OLUWA; àwọn tí ó bá sì kórè àjàrà ni yóo mu ọtí rẹ̀, ninu àgbàlá ilé mímọ́ mi. Ẹ kọjá! Ẹ gba ẹnubodè kọjá, ẹ tún ọ̀nà ṣe fún àwọn eniyan. Ẹ la ọ̀nà, ẹ la òpópónà, kí ẹ ṣa òkúta kúrò níbẹ̀. Ẹ ta àsíá sókè, fún àwọn eniyan náà. Wò ó! OLUWA ti kéde títí dé òpin ayé. Ó ní, “Ẹ sọ fún àwọn ará Jerusalẹmu pé, ‘Wò ó, olùgbàlà yín ti dé, èrè rẹ wà pẹlu rẹ̀, ẹ̀san rẹ sì wà níwájú rẹ̀.’ ” A óo máa pè yín ní, “Eniyan mímọ́”, “Ẹni-Ìràpadà-OLUWA”. Wọn óo máa pè yín ní, “Àwọn-tí-a-wá-ní-àwárí”; wọn óo sì máa pe Jerusalẹmu ní, “Ìlú tí a kò patì”. “Ta ni ń ti Edomu bọ̀ yìí, tí ó wọ aṣọ àlàárì, tí ń bọ̀ láti Bosira, tí ó yọ bí ọjọ́ ninu aṣọ tí ó wọ̀, tí ń yan bọ̀ ninu agbára ńlá rẹ̀.” “Èmi ni, èmi tí mò ń kéde ẹ̀san, tí mo sì lágbára láti gbani là.” “Kí ló dé tí aṣọ rẹ fi pupa, tí ó dàbí ti ẹni tí ń fún ọtí waini?” OLUWA dáhùn, ó ní, “Èmi nìkan ni mo tí ń fún ọtí waini, ẹnikẹ́ni kò bá mi fún un ninu àwọn eniyan mi. Mo fi ibinu tẹ̀ wọ́n bí èso àjàrà, mo fi ìrúnú tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀. Ẹ̀jẹ̀ wọn bá dà sí mi láṣọ: ó ti di àbààwọ́n sára gbogbo aṣọ mi. Nítorí ọjọ́ ẹ̀san ló wà lọ́kàn mi, ọdún ìràpadà mi sì ti dé. Mo wò yíká, ṣugbọn kò sí olùrànlọ́wọ́, ẹnu yà mí pé, n kò rí ẹnìkan tí yóo gbé mi ró; nítorí náà, agbára mi ni mo fi ṣẹgun, ibinu mi ni ó sì gbé mi ró. Mo fi ibinu tẹ àwọn orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀, mo fi ìrúnú rọ wọ́n yó, mo sì tú ẹ̀jẹ̀ wọn dà sílẹ̀.” N óo máa sọ nípa ìfẹ́ ńlá OLUWA lemọ́lemọ́, n óo máa kọrin ìyìn rẹ̀; nítorí gbogbo ohun tí OLUWA ti fún wa, ati oore ńlá tí ó ṣe fún ilé Israẹli, tí ó ṣe fún wọn nítorí àánú rẹ̀, ati gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀. OLUWA ní, “Dájúdájú eniyan mi mà ni wọ́n, àwọn ọmọ tí kò ní hùwà àgàbàgebè.” Ó sì di Olùgbàlà wọn. Ninu gbogbo ìyà tí wọ́n jẹ, òun pẹlu wọn ni, angẹli iwájú rẹ̀ sì gbà wọ́n là. Nítorí ìfẹ́ ati àánú rẹ̀, ó rà wọ́n pada. Ó fà wọ́n sókè, ó sì gbé wọn ní gbogbo ìgbà àtijọ́. Ṣugbọn wọ́n hùwà ọlọ̀tẹ̀: wọ́n sì mú Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ bínú. Nítorí náà ó di ọ̀tá wọn, ó sì dojú ìjà kọ wọ́n. Ṣugbọn ó ranti ìgbà àtijọ́, ní àkókò Mose, iranṣẹ rẹ̀. Wọ́n bèèrè pé, ẹni tí ó kó wọn la òkun já dà? Olùṣọ́-aguntan agbo rẹ̀, tí ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ sáàrin wọn? Ẹni tí ó gbé agbára rẹ̀ tí ó lógo wọ Mose, tí ó pín òkun níyà níwájú wọn, kí orúkọ rẹ̀ lè lókìkí títí lae. Ó mú wọn la ibú omi kọjá, bí ẹṣin ninu aṣálẹ̀; wọ́n rìn, wọn kò fẹsẹ̀ kọ. Wọ́n rìn wọnú àfonífojì bíi mààlúù, Ẹ̀mí OLUWA sì fún wọn ní ìsinmi. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe darí àwọn eniyan rẹ̀, kí ó lè gba ògo fún orúkọ rẹ̀. Bojúwo ilẹ̀ láti ọ̀run, láti ibùgbé rẹ mímọ́ tí ó lógo. Ìtara rẹ dà? Agbára rẹ dà? O ti dáwọ́ ìfẹ́ ati àánú rẹ dúró lára wa ni? Ìwọ ni baba wa. Bí Abrahamu kò tilẹ̀ mọ̀ wá, tí Israẹli kò sì dá wa mọ̀. Ìwọ OLUWA ni baba wa, Olùràpadà wa láti ìgbà àtijọ́, ni orúkọ rẹ. OLUWA kí ló dé tí o fi jẹ́ kí á ṣìnà, kúrò lọ́dọ̀ rẹ; tí o sé ọkàn wa lé, tí a kò fi bẹ̀rù rẹ? Pada sọ́dọ̀ wa nítorí àwọn iranṣẹ rẹ, nítorí àwọn ẹ̀yà Israẹli tíí ṣe ìní rẹ. Fún ìgbà díẹ̀, ilé mímọ́ rẹ jẹ́ ti àwa eniyan mímọ́ rẹ; ṣugbọn àwọn ọ̀tá wa ti wó o lulẹ̀. A wá dàbí àwọn tí o kò jọba lórí wọn rí, àní, bí àwọn tí a kò fi orúkọ rẹ pè. Ò bá jẹ́ fa awọsanma ya kí o sì sọ̀kalẹ̀, kí àwọn òkè ńlá máa mì tìtì níwájú rẹ; bí ìgbà tí iná ń jó igbó ṣúúrú, tí iná sì ń mú kí omi hó. Kí orúkọ rẹ di mímọ̀ fún àwọn ọ̀tá rẹ, kí àwọn orílẹ̀-èdè lè máa gbọ̀n níwájú rẹ! Nígbà tí o bá ṣe nǹkan tí ó bani lẹ́rù, tí ẹnikẹ́ni kò retí, o sọ̀kalẹ̀, àwọn òkè ńlá sì mì tìtì níwájú rẹ. Láti ìgbà àtijọ́, ẹnìkan kò gbọ́ rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò tíì fi ojú rí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn rẹ, tí ń ṣe irú nǹkan wọnyi fún àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e. Ò máa ran àwọn tí ń fi inú dídùn ṣiṣẹ́ òdodo lọ́wọ́, àwọn tí wọn ranti rẹ ninu ìgbé ayé wọn, o bínú, nítorí náà a dẹ́ṣẹ̀, a ti wà ninu ẹ̀ṣẹ̀ wa tipẹ́. Ǹjẹ́ a óo rí ìgbàlà? Gbogbo wa dàbí aláìmọ́, gbogbo iṣẹ́ òdodo wa dàbí àkísà ẹlẹ́gbin. Gbogbo wa rọ bí ewé, àìdára wa sì ń fẹ́ wa lọ bí atẹ́gùn. Kò sí ẹnìkan tí ń gbadura ní orúkọ rẹ, kò sí ẹni tí ń ta ṣàṣà láti dìmọ́ ọ; nítorí pé o ti fojú pamọ́ fún wa, o sì ti pa wá tì nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa. Sibẹsibẹ OLUWA, ìwọ ni baba wa, amọ̀ ni wá, ìwọ sì ni amọ̀kòkò; iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ni gbogbo wa. OLUWA má bínú pupọ jù, má máa ranti ẹ̀ṣẹ̀ wa títí lae. Jọ̀wọ́, ro ọ̀rọ̀ wa wò, nítorí pé eniyan rẹ ni gbogbo wa. Àwọn ìlú mímọ́ rẹ ti di aṣálẹ̀, Sioni ti di aṣálẹ̀, Jerusalẹmu sì ti di ahoro. Wọ́n ti dáná sun ilé mímọ́ wa tí ó lẹ́wà, níbi tí àwọn baba wa ti yìn ọ́, gbogbo ibi dáradára tí a ní, ló ti di ahoro. OLUWA, ṣé o kò ní ṣe nǹkankan sí ọ̀rọ̀ yìí ni? Ṣé o óo dákẹ́, o óo máa fìyà jẹ wá ni? Mo ṣetán láti mú kí àwọn tí kò bèèrè mi máa wá mi, ati láti fi ara mi han àwọn tí kò wá mi. Mo sọ fún orílẹ̀-èdè tí kì í gbadura ní orúkọ mi pé, “Èmi nìyí, èmi nìyí.” Láti òwúrọ̀ di alẹ́, mo na ọwọ́ mi sí àwọn ọlọ̀tẹ̀ eniyan; àwọn tí wọn ń rìn ní ọ̀nà tí kò dára, tí wọn ń tẹ̀lé èrò ọkàn wọn, tí wọn ń ṣe ohun tí yóo mú mi bínú, níṣojú mi, nígbà gbogbo. Wọ́n ń rúbọ ninu oríṣìíríṣìí ọgbà, wọ́n ń sun turari lórí bíríkì. Àwọn tí wọn ń jókòó sí itẹ́ òkú, tí wọn ń dúró níbi ìkọ̀kọ̀ lóru; àwọn tí wọn ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀, tí ìṣaasùn ọbẹ̀ wọn sì kún fún ẹran aláìmọ́. Wọn á máa ké pé, “Yàgò lọ́nà. Má fara kàn mí, nítorí mo jẹ́ ẹni mímọ́ jù ọ́ lọ.” Ṣugbọn bí èéfín ni irú wọn rí ní ihò imú mi, bí iná tí ó ń jó lojoojumọ. Wò ó! A ti kọ ọ́ sílẹ̀ níwájú mi pé, “N kò ní dákẹ́, ṣugbọn n óo gbẹ̀san. N óo gbẹ̀san gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn lára wọn, ati ti àwọn baba wọn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Nítorí pé wọ́n ń sun turari lórí àwọn òkè ńlá, wọ́n sì ń fi mí ṣẹ̀sín lórí àwọn òkè kéékèèké. N óo san ẹ̀san iṣẹ́ wọn àtẹ̀yìnwá fún wọn. “Bí eniyan tíí wòye pé ọtí wà lára ìdì èso àjàrà, tí wọn sìí sọ pé, ‘Ẹ má bà á jẹ́, nítorí ohun rere wà ninu rẹ̀,’ bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe nítorí iranṣẹ mi, n kò ní pa gbogbo wọn run. N óo mú kí arọmọdọmọ jáde lára Jakọbu, àwọn tí yóo jogún òkè ńlá mi yóo sì jáde láti ara Juda. Àwọn tí mo ti yàn ni yóo jogún rẹ̀, àwọn iranṣẹ mi ni yóo sì máa gbé ibẹ̀. Ilé Ṣaroni yóo di ibùjẹ ẹran, àfonífojì Akori yóo sì di ibi tí àwọn ẹran ọ̀sìn yóo máa dùbúlẹ̀ sí, fún àwọn eniyan mi, tí wọ́n wá mi. “Ṣugbọn níti ẹ̀yin tí ẹ kọ mí sílẹ̀, tí ẹ gbàgbé Òkè Mímọ́ mi, tí ẹ tẹ́ tabili sílẹ̀ fún Gadi, oriṣa Oríire, tí ẹ̀ ń po àdàlú ọtí fún Mẹni, oriṣa Àyànmọ́. N óo fi yín fún ogun pa, gbogbo yín ni ẹ óo sì bọ́ sọ́wọ́ àwọn apànìyàn; nítorí pé nígbà tí mo pè yín, ẹ kò dáhùn, nígbà tí mo sọ̀rọ̀, ẹ kò gbọ́, ẹ ṣe nǹkan tí ó burú lójú mi; ẹ yan ohun tí inú mi kò dùn sí. Wò ó, àwọn iranṣẹ mi yóo máa rí oúnjẹ jẹ, ṣugbọn ebi yóo máa pa yín; àwọn iranṣẹ mi yóo mu waini, ṣugbọn òùngbẹ yóo máa gbẹ yín. Àwọn iranṣẹ mi yóo máa yọ̀, ṣugbọn ìtìjú yóo máa ba yín. Àwọn iranṣẹ mi yóo máa kọrin nítorí inú wọn dùn, ṣugbọn ẹ̀yin óo máa kígbe oró àtọkànwá; ẹ óo sì máa sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, nítorí àròkàn. Orúkọ tí ẹ óo fi sílẹ̀ fún àwọn àyànfẹ́ mi yóo di ohun tí wọn yóo máa fi gégùn-ún. Èmi Oluwa Ọlọrun óo pa yín. Ṣugbọn n óo pe àwọn iranṣẹ mi ní orúkọ mìíràn. Dé ibi pé ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ tọrọ ibukun ní ilẹ̀ náà, yóo máa tọrọ rẹ̀ ní orúkọ Ọlọrun òtítọ́, ẹnikẹ́ni tí yóo bá sì búra ní ilẹ̀ náà, orúkọ Ọlọrun òtítọ́ ni yóo máa fi búra. Àwọn ìṣòro àtijọ́ yóo ti di ohun ìgbàgbé, a óo sì ti fi wọ́n pamọ́ kúrò níwájú mi.” OLUWA ní, “Mo dá ọ̀run tuntun, ati ayé tuntun; a kò ní ranti àwọn ohun àtijọ́ mọ́, tabi kí wọn sọ sí eniyan lọ́kàn. Ṣugbọn ẹ jẹ́ kí inú yín ó máa dùn, kí ẹ sì máa yọ títí lae, ninu ohun tí mo dá. Wò ó! Mo dá Jerusalẹmu ní ìlú aláyọ̀, mo sì dá àwọn eniyan inú rẹ̀ ní onínú dídùn. N óo láyọ̀ ninu Jerusalẹmu, inú mi óo sì máa dùn sí àwọn eniyan mi. A kò ní gbọ́ igbe ẹkún ninu rẹ̀ mọ́, ẹnikẹ́ni kò sì ní sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn ninu rẹ̀ mọ́. Ọmọ tuntun kò ní kú ní Jerusalẹmu mọ́, àwọn àgbààgbà kò sì ní kú láìjẹ́ pé wọ́n darúgbó kùjọ́kùjọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ikú ọ̀dọ́ ni a óo máa pe ikú ẹni tí ó bá kú ní ẹni ọgọrun-un ọdún. Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ bá kú ní ẹni ọgọrun-un ọdún, a óo sọ pé ó kú ikú ègún. Wọn óo kọ́ ilé, wọn óo gbé inú rẹ̀; wọn óo gbin ọgbà àjàrà, wọn óo sì jẹ èso rẹ̀. Wọn kò ní kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé, wọn kò sì ní gbin ọgbà àjàrà fún ẹlòmíràn jẹ. Àwọn eniyan mi yóo pẹ́ láyé bí igi ìrókò, àwọn àyànfẹ́ mi yóo sì jèrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Wọn kò ní ṣe iṣẹ́ àṣedànù, wọn kò ní bímọ fún jamba; nítorí ọmọ ẹni tí OLUWA bukun ni wọn yóo jẹ́, àwọn ati àwọn ọmọ wọn. Kí wọn tó pè mí, n óo ti dá wọn lóhùn, kí wọn tó sọ̀rọ̀ tán, n óo ti gbọ́ ohun tí wọ́n fẹ́ sọ. Ìkookò ati ọmọ aguntan yóo jọ máa jẹ káàkiri; kinniun yóo máa jẹ koríko bíi mààlúù, erùpẹ̀ ni ejò yóo máa jẹ, wọn kò ní máa panilára. Wọn kò sì ní máa panirun lórí òkè mímọ́ mi mọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA ní: “Ọ̀run ni ìtẹ́ mi, ayé ni àpótí ìtìsẹ̀ mi. Ilé tí ẹ kọ́ fún mi dà? Níbo sì ni ibi ìsinmi mi wà? Ọwọ́ mi ni mo fi ṣe gbogbo nǹkan wọnyi, tèmi sì ni gbogbo wọn. Ẹni tí n óo kà kún, ni onírẹ̀lẹ̀ ati oníròbìnújẹ́ eniyan, tí ó ń wárìrì nítorí ọ̀rọ̀ mi. “Ati ẹni tí ó pa mààlúù rúbọ, ati ẹni tí ó pa eniyan; kò sí ìyàtọ̀. Ẹni tí ó fi ọ̀dọ́ aguntan rúbọ, kò yàtọ̀ sí ẹni tí ó lọ́ ajá lọ́rùn pa. Ati ẹni tí ó fi ọkà rúbọ, ati ẹni tí ó fi ẹ̀jẹ̀ ẹlẹ́dẹ̀ rúbọ, bákan náà ni wọ́n rí. Ẹni tí ó fi turari ṣe ẹbọ ìrántí, kò sì yàtọ̀ sí ẹni tí ó súre níwájú oriṣa. Wọ́n ti yan ọ̀nà tí ó wù wọ́n, wọ́n sì ń fi tọkàntọkàn sin ohun ìríra wọn. Èmi náà óo sì yan ìjìyà fún wọn, n óo jẹ́ kí ẹ̀rù wọn pada sórí wọn. Nítorí pé nígbà tí mo pè wọ́n, ẹnikẹ́ni wọn kò dáhùn; nígbà tí mo sọ̀rọ̀ fún wọn, wọn kò gbọ́, wọ́n ṣe ohun tí ó burú lójú mi, wọ́n yan ohun tí inú mi kò dùn sí.” Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wárìrì nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀: “Àwọn arakunrin yín tí wọn kórìíra yín, wọ́n tì yín síta nítorí orúkọ mi; wọ́n ní, ‘Jẹ́ kí OLUWA fi ògo rẹ̀ hàn, kí á lè rí ayọ̀ yín.’ Ṣugbọn àwọn ni ojú yóo tì. Ẹ gbọ́ ariwo ninu ìlú, ẹ gbọ́ ohùn kan láti inú Tẹmpili, ohùn OLUWA ni, ó ń san ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá rẹ̀. “Kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí rọbí, ó ti bímọ. Kí ìrora obí tó mú un, ó ti bí ọmọkunrin kan. Ta ló gbọ́ irú èyí rí? Ta ló rí irú rẹ̀ rí? Ǹjẹ́ a lè bí ilẹ̀ ní ọjọ́ kan, tabi kí á bí orílẹ̀-èdè kan ní ọjọ́ kan? Ní kété tí Sioni bẹ̀rẹ̀ sí rọbí, ni ó bí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin. Ṣé mo lè jẹ́ kí eniyan máa rọbí, kí n má jẹ́ kí ó bímọ bí? Èmi OLUWA, tí mò ń mú kí eniyan máa bímọ, ṣé, mo jẹ́ sé eniyan ninu?” Ẹ bá Jerusalẹmu yọ̀, kí inú yín dùn nítorí rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn rẹ̀, ẹ bá a yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀ nítorí rẹ̀. Kí ẹ lè mu àmutẹ́rùn, ninu wàrà rẹ̀ tí ń tuni ninu; kí ẹ lè ní ànítẹ́rùn pẹlu ìdùnnú, ninu ọpọlọpọ ògo rẹ̀. Nítorí OLUWA ní: “N óo tú ibukun sórí rẹ̀, bí ìgbà tí odò bá ń ṣàn. N óo da ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́, bí odò tí ò ṣàn kọjá bèbè. Yóo dà yín sẹ́gbẹ̀ẹ́ bí ọmọ tí ń mu ọmú, ẹ óo máa ṣeré lórí orúnkún rẹ̀. N óo rẹ̀ yín lẹ́kún bí ọmọ tí ìyá rẹ̀ rẹ̀ lẹ́kún, bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe tù yín ninu ní Jerusalẹmu. Ẹ óo rí i, inú yín yóo dùn, egungun yín yóo sọjí, bí ìgbà tí koríko bá rúwé. Gbogbo eniyan yóo sì mọ̀ pé ọwọ́ OLUWA wà lára àwọn iranṣẹ rẹ̀, ati pé inú bí i sí àwọn ọ̀tá rẹ̀.” Wò ó! OLUWA ń bọ̀ ninu iná, kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ yóo dàbí ìjì, láti fi ìrúnú san ẹ̀san, yóo sì fi ahọ́n iná báni wí. Nítorí pé iná ni OLUWA yóo fi ṣe ìdájọ́, idà ni yóo fi ṣe ìdájọ́ fún gbogbo eniyan; àwọn tí OLUWA yóo fi idà pa yóo sì pọ̀. OLUWA ní, “Àwọn tí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀, tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n ń lọ bọ̀rìṣà ninu àgbàlá, wọ́n ń jó ijó oriṣa, wọ́n ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀, ati àwọn ohun ìríra, ati èkúté! Gbogbo wọn ni yóo ṣègbé papọ̀. Nítorí mo mọ iṣẹ́ ọwọ́ wọn ati èrò ọkàn wọn. Mò ń bọ̀ wá gbá gbogbo orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà jọ. Nígbà tí wọ́n bá dé, wọ́n óo rí ògo mi. “N óo sì gbé àmì kan kalẹ̀ láàrin wọn. N óo rán àwọn tí ó yè lára wọn sí àwọn orílẹ̀-èdè; àwọn bíi: Taṣiṣi, Puti, ati Ludi, ilẹ̀ àwọn tafàtafà, ati Tubali ati Jafani, ati àwọn erékùṣù tí ó jìnnà réré; àwọn tí kò tíì gbọ́ òkìkí mi, tí wọn kò sì tíì rí ògo mi rí. Wọn óo sì ròyìn ògo mi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè. Wọn óo sì kó gbogbo àwọn ará yín bọ̀ láti orílẹ̀-èdè gbogbo, wọn óo kó wọn wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fún OLUWA. Wọn óo máa bọ̀ lórí ẹṣin, lórí kẹ̀kẹ́-ogun, lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ati ràkúnmí, wọn óo máa wá sí ìlú Jerusalẹmu, òkè mímọ́ mi, bí àwọn ọmọ Israẹli yóo ti máa mú ẹbọ ohun jíjẹ wọn wá sí ilé OLUWA, ninu àwo tí ó mọ́. N óo mú ninu wọn, n óo fi ṣe alufaa ati ọmọ Lefi. “Bí ọ̀run tuntun ati ayé tuntun tí n óo dá, yóo ṣe máa wà níwájú mi, bẹ́ẹ̀ ni arọmọdọmọ ati orúkọ rẹ̀ yóo máa wà. Láti oṣù tuntun dé oṣù tuntun, ati láti ọjọ́ ìsinmi kan dé ekeji, ni gbogbo eniyan yóo máa wá jọ́sìn níwájú mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Wọn óo jáde, wọn óo sì fojú rí òkú àwọn tí ó ṣọ̀tẹ̀ sí mi; nítorí ìdin tí ń jẹ wọ́n kò ní kú, bẹ́ẹ̀ ni iná tí ń jó wọn kò ní kú; wọn óo sì jẹ́ ohun ìríra lójú gbogbo eniyan.” Ọ̀rọ̀ Jeremaya, ọmọ Hilikaya, ọ̀kan ninu àwọn alufaa tí ó wà ní Anatoti, ní ilẹ̀ Bẹnjamini nìyí. Nígbà ayé Josaya, ọmọ Amoni, ọba Juda, ní ọdún kẹtala tí Josaya gun orí oyè ni OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀. Ó sì tún gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA ní ìgbà ayé Jehoiakimu, ọmọ Josaya, ọba Juda títí di òpin ọdún kọkanla tí Sedekaya ọmọ Josaya jọba ní ilẹ̀ Juda, títí tí ogun fi kó Jerusalẹmu ní oṣù karun-un ọdún náà. OLUWA sọ fún mi pé, “Kí n tó dá ọ sinu ìyá rẹ ni mo ti mọ̀ ọ́, kí wọ́n sì tó bí ọ ni mo ti yà ọ́ sọ́tọ̀, mo yàn ọ́ ní wolii fún àwọn orílẹ̀-èdè.” Mo bá dáhùn pé, “Háà! OLUWA Ọlọrun! Wò ó! N kò mọ ọ̀rọ̀ sọ, nítorí pé ọmọde ni mí.” Ṣugbọn OLUWA dá mi lóhùn, ó ní, “Má pe ara rẹ ní ọmọde, nítorí pé gbogbo ẹni tí mo bá rán ọ sí ni o gbọdọ̀ tọ̀ lọ. Gbogbo ohun tí mo bá pa láṣẹ fún ọ ni o gbọdọ̀ sọ. Má bẹ̀rù wọn, nítorí mo wà pẹlu rẹ, n óo sì gbà ọ́.” OLUWA bá na ọwọ́, ó fi kàn mí lẹ́nu, ó sì wí fún mi pé, “Wò ó, mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ọ lẹ́nu. Mo ti fi ọ́ ṣe orí fún àwọn orílẹ̀-èdè ati ìjọba lónìí, láti fà wọ́n tu ati láti bì wọ́n lulẹ̀, láti pa wọ́n run ati láti bì wọ́n ṣubú, láti tún wọn kọ́ ati láti gbé wọn ró.” OLUWA bi mí pé, “Jeremaya, kí ni o rí yìí?” Mo dáhùn, pé, “Ọ̀pá igi Alimọndi ni.” OLUWA bá wí fún mi pé, “Òtítọ́ ni ohun tí o rí, nítorí mò ń sọ ọ̀rọ̀ tí mo sọ, n óo sì mú un ṣẹ.” OLUWA tún bi mí lẹẹkeji, ó ní, “Kí ni o rí?” Mo bá dáhùn pé, “Mo rí ìkòkò kan tí ó ń hó lórí iná, ó tẹ̀ láti ìhà àríwá sí ìhà gúsù.” OLUWA bá sọ fún mi pé, “Láti ìhà àríwá ni ibi yóo ti dé bá gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà. Nítorí pé mò ń pe gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní ìjọba àríwá, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, àwọn ọba wọn yóo sì tẹ́ ìtẹ́ wọn kalẹ̀ ní ẹnubodè Jerusalẹmu, ati yíká odi gbogbo ìlú Juda. N óo dá wọn lẹ́jọ́ nítorí gbogbo ibi tí wọ́n ti ṣe, tí wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀, tí wọn ń sun turari fún àwọn oriṣa, tí wọ́n sì ń bọ ohun tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe. Ṣugbọn, ìwọ dìde, di àmùrè rẹ, kí o sì sọ gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ fún wọn. Má jẹ́ kí ẹ̀rù wọn ó bà ọ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, n óo dẹ́rù bà ọ́ níwájú wọn. Wò ó, mo ti sọ ọ́ di ìlú tí a mọ odi yíká lónìí, o di òpó irin ati ògiri tí a fi bàbà mọ fún gbogbo ilẹ̀ yìí, ati fún àwọn ọba ilẹ̀ Juda, àwọn ìjòyè, ati àwọn alufaa rẹ̀, ati àwọn eniyan ilẹ̀ náà. Wọn yóo gbógun tì ọ́, ṣugbọn wọn kò ní ṣẹgun rẹ. Nítorí pé mo wà pẹlu rẹ láti gbà ọ́ kalẹ̀. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA sọ fún mi pé, “Lọ kéde sí etígbọ̀ọ́ àwọn ará Jerusalẹmu, pé èmi OLUWA ní, mo ranti bí o ti fi ara rẹ jì mí nígbà èwe rẹ, ìfẹ́ rẹ dàbí ìfẹ́ iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé; mo ranti bí o ṣe ń tẹ̀lé mi ninu aṣálẹ̀, ní ilẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbin nǹkankan sí. Israẹli jẹ́ mímọ́ fún OLUWA Òun ni àkọ́so èso rẹ̀. Gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ ninu àkọ́so èso yìí di ẹlẹ́bi; ibi sì dé bá wọn. Èmi OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.” Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ̀yin ilé Jakọbu, ati gbogbo ìdílé Israẹli. OLUWA ní: “Nǹkan burúkú wo ni àwọn baba ńlá yín ní mo fi ṣe àwọn, tí wọ́n jìnnà sí mi; tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ síí bọ oriṣa lásánlàsàn, tí àwọn pàápàá sì fi di eniyan lásán? Wọn kò bèèrè pé, Níbo ni OLUWA wà, ẹni tí ó kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti, tí ó sìn wá la aṣálẹ̀ já, ilẹ̀ aṣálẹ̀ tí ó kún fún ọ̀gbun, ilẹ̀ ọ̀dá ati òkùnkùn biribiri, ilẹ̀ tí eniyan kìí là kọjá, tí ẹnikẹ́ni kì í gbé? Mo mu yín wá sí ilẹ̀ tí ó lọ́ràá, pé kí ẹ máa gbádùn èso rẹ̀ ati àwọn nǹkan dáradára tí wọ́n wà ninu rẹ̀, ṣugbọn nígbà tí ẹ dé inú rẹ̀, ẹ sọ ilẹ̀ mi di aláìmọ́, ẹ sì sọ ogún mi di ohun ìríra. Àwọn alufaa kò bèèrè pé, ‘OLUWA dà?’ Àwọn tí wọn ń ṣe àmójútó òfin kò mọ̀ mí, àwọn olórí ń dìtẹ̀ sí mi, àwọn wolii ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ oriṣa Baali, wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn oriṣa lásánlàsàn. “Nítorí náà, mò ń ba yín rojọ́, n óo sì tún bá arọmọdọmọ yín rojọ́ pẹlu.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. Ó ní, “Ẹ kọjá sí èbúté àwọn ará Kipru kí ẹ wò yíká, tabi kí ẹ ranṣẹ sí Kedari kí ẹ sì ṣe ìwádìí fínnífínní, bóyá irú rẹ̀ ṣẹlẹ̀ rí. Ǹjẹ́ orílẹ̀-èdè kankan tíì pààrọ̀ ọlọrun rẹ̀ rí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe ọlọrun tòótọ́? Ṣugbọn àwọn eniyan mi ti pààrọ̀ ògo wọn, wọ́n ti fi ohun tí kò ní èrè pààrọ̀ rẹ̀. Nítorí náà kí ẹ̀rù kí ó bà ọ́, ìwọ ọ̀run, kí o wárìrì, kí gbogbo nǹkan dàrú mọ́ ọ lójú.” OLUWA wí pé, “Nítorí pé àwọn eniyan mi ṣe nǹkan burúkú meji: wọ́n ti kọ èmi orísun omi ìyè sílẹ̀, wọ́n ṣe kànga fún ara wọn; kànga tí ó ti là, tí kò lè gba omi dúró. “Ṣé ẹrú ni Israẹli ni, àbí ọmọ ẹrú tí ẹrú bí sinu ilé? Báwo ló ṣe wá di ìjẹ fún àwọn ọ̀tá rẹ̀. Àwọn kinniun ti bú mọ́ ọn, wọ́n bú ramúramù. Wọ́n sọ ilẹ̀ rẹ̀ di ahoro. Àwọn ìlú rẹ̀ sì ti tú, wọ́n ti wó palẹ̀, láìsí eniyan tí ń gbé inú wọn. Bákan náà, àwọn ará Memfisi ati Tapanhesi ti fọ́ adé orí rẹ̀. Ṣebí ọwọ́ ara yín ni ẹ fi fà á sí orí ara yín, nígbà tí ẹ̀yin kọ Ọlọrun yín sílẹ̀, nígbà tí ó ń tọ yín sọ́nà? Kí ni èrè tí ẹ rí nígbà tí ẹ lọ sí Ijipti, tí ẹ lọ mu omi odò Naili, àbí kí ni èrè tí ẹ gbà bọ̀ nígbà tí ẹ lọ sí Asiria, tí ẹ lọ mu omi odò Yufurate. Ìwà burúkú yín yóo fìyà jẹ yín, ìpadà sẹ́yìn yín yóo sì kọ yín lọ́gbọ́n. Kí ó da yín lójú pé, nǹkan burúkú ni, ìgbẹ̀yìn rẹ̀ kò sì ní dùn, pé ẹ fi èmi OLUWA Ọlọrun yín sílẹ̀; ìbẹ̀rù mi kò sí ninu yín. Èmi, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA wí pé, “Nítorí pé ó ti pẹ́ tí ẹ ti bọ́ àjàgà yín, tí ẹ sì ti tú ìdè yín; tí ẹ sọ pé, ẹ kò ní sìn mí. Ẹ̀ ń lọ káàkiri lórí gbogbo òkè, ati lábẹ́ gbogbo igi tútù; ẹ̀ ń foríbalẹ̀, ẹ̀ ń ṣe bíi panṣaga. Sibẹ mo gbìn yín gẹ́gẹ́ bí àjàrà tí mo fẹ́, tí èso rẹ̀ dára. Báwo ni ẹ ṣe wá yipada patapata, tí ẹ di àjàrà igbó tí kò wúlò? Bí ẹ tilẹ̀ fi eérú fọ ara yín, tí ẹ sì fi ọpọlọpọ ọṣẹ wẹ̀, sibẹ, àbààwọ́n ẹ̀bi yín wà níwájú mi. Báwo ní ẹ ṣe lè wí pé ẹ kì í ṣe aláìmọ́; ati pé ẹ kò tẹ̀lé àwọn oriṣa Baali? Ẹ wo irú ìwà tí ẹ hù ninu àfonífojì, kí ẹ ranti gbogbo ibi tí ẹ ṣe bí ọmọ ràkúnmí tí ń lọ, tí ń bọ̀; tí ń tọ ipa ọ̀nà ara rẹ̀. Ẹ dàbíi Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́, tí aṣálẹ̀ ti mọ́ lára, tí ń ṣí imú kiri, nígbà tí ó ń wa akọ tí yóo gùn ún. Ta ló lè dá a dúró? Kí akọ tí ó bá ń wá a má wulẹ̀ ṣe ara rẹ̀ ní wahala, nítorí yóo yọjú nígbà tí àkókò gígùn rẹ̀ bá tó. Má rìn láìwọ bàtà, Israẹli, má sì jẹ́ kí òùngbẹ gbẹ ọ́. Ṣugbọn o sọ pé, ‘Kò sí ìrètí, nítorí àjèjì oriṣa ni mo fẹ́, n óo sì wá wọn kiri.’ ” OLUWA ní, “Bí ojú tíí ti olè nígbà tí ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ojú yóo tì yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli. Àtẹ̀yin ati àwọn ọba yín, ati àwọn ìjòyè yín, ati àwọn alufaa yín, ati àwọn wolii yín; ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wí fún igi pé igi ni baba yín, tí ẹ sì ń sọ fún òkúta pé òkúta ni ó bi yín; nítorí pé dípò kí ẹ kọjú sí ọ̀dọ̀ mi, ẹ̀yìn ni ẹ kọ sí mi. Ṣugbọn nígbà tí ìṣòro dé ba yín, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pè mí pé kí n dìde, kí n gbà yín là. “Ṣugbọn níbo ni àwọn oriṣa yín tí ẹ dá fún ara yín wà? Kí wọn dìde, tí wọ́n bá lè gbà yín ní àkókò ìṣòro yín! Ṣebí bí ìlú yín ti pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni àwọn oriṣa yín náà pọ̀ tó, ẹ̀yin ará Juda. Ẹjọ́ kí ni ẹ wá ń bá mi rò? Ṣebí gbogbo yín ni ẹ̀ ń bá mi ṣọ̀tẹ̀! Mo na àwọn ọmọ yín lásán ni, wọn kò gba ẹ̀kọ́. Ẹ̀yin gan-an ni ẹ fi idà pa àwọn wolii yín ní àparun, bíi kinniun tí ń pa ẹran kiri. Ẹ̀yin ìran yìí, ẹ gbọ́ ohun tí èmi, OLUWA ń sọ. Ṣé aṣálẹ̀ ni mo jẹ́ fún Israẹli; tabi mo ti di ilẹ̀ òkùnkùn biribiri? Kí ló dé tí ẹ̀yin eniyan mi fí ń sọ pé, ‘A ti di òmìnira, a lè máa káàkiri; a kò ní wá sí ọ̀dọ̀ rẹ mọ́?’ Ṣé ọmọbinrin lè gbàgbé ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀? Tabi iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé lè gbàgbé àwọn aṣọ rẹ̀? Sibẹ ẹ ti gbàgbé mi tipẹ́. “Ẹ mọ oríṣìíríṣìí ọ̀nà tí eniyan fi í wá olólùfẹ́ kiri, tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ ti fi ìrìnkurìn yín kọ́ àwọn obinrin oníwà burúkú. Ẹ̀jẹ̀ àwọn talaka tí kò ṣẹ̀, wà létí aṣọ yín; bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò bá wọn níbi tí wọ́n ti ń fọ́lé. Gbogbo èyí wà bẹ́ẹ̀, sibẹ ẹ̀ ń sọ pé, ‘Ọwọ́ wa mọ́; dájúdájú, OLUWA ti dá ọwọ́ ibinu rẹ̀ dúró lára wa.’ Ẹ wò ó! N óo dá yín lẹ́jọ́, nítorí ẹ̀ ń sọ pé ẹ kò dẹ́ṣẹ̀. Ẹ̀ ń fi ara yín wọ́lẹ̀ káàkiri; ẹ̀ ń yà síhìn-ín sọ́hùn-ún! Bí Asiria ti dójú tì yín, bẹ́ẹ̀ ni Ijipti náà yóo dójú tì yín. Ẹ óo ká ọwọ́ lérí ni nígbà tí ẹ óo bá jáde níbẹ̀. Nítorí OLUWA ti kọ àwọn tí ẹ gbójúlé, wọn kò sì ní ṣe yín níre.” OLUWA ní, “Ṣé bí ọkọ bá kọ iyawo rẹ̀ sílẹ̀, tí iyawo náà sì kó jáde nílé ọkọ, tí ó lọ fẹ́ ẹlòmíràn, ṣé ọkọ rẹ̀ àkọ́kọ́ lè tún lọ gbà á pada? Ṣé ilẹ̀ náà kò ní di ìbàjẹ́? Lẹ́yìn tí ẹ ti ṣe àgbèrè pẹlu ọpọlọpọ olólùfẹ́; ẹ wá fẹ́ pada sọ́dọ̀ mi? Ẹ gbójú sókè kí ẹ wo gbogbo òkè yíká, ibo ni ẹ kò tíì ṣe àgbèrè dé? Ẹ̀ ń dúró de olólùfẹ́ lẹ́bàá ọ̀nà, bí àwọn obinrin Arabia ninu aṣálẹ̀. Ẹ ti fi ìṣekúṣe yín ba ilẹ̀ náà jẹ́. Nítorí náà ni òjò kò ṣe rọ̀, tí òjò àkọ́rọ̀ kò rọ̀ ní àkókò tí ó yẹ. Sibẹsibẹ, ẹ̀ ń gbéjú gbéré bí aṣẹ́wó, ojú kò sì tì yín. Israẹli, o wá ń pè mí nisinsinyii, ò ń sọ pé, ‘Ìwọ ni baba mi, ìwọ ni ọ̀rẹ́ mi láti ìgbà èwe mi. Ṣé o kò ní dáwọ́ ibinu rẹ dúró ni? Tabi títí ayé ni o óo fi máa bínú?’ Lóòótọ́ o ti sọ bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀, ṣugbọn o ti ṣe ìwọ̀n ibi tí o lè ṣe.” OLUWA sọ fún mi ní ìgbà ayé ọba Josaya pé: “Ṣé o rí ohun tí Israẹli, alaiṣootọ ẹ̀dá ṣe? Ṣé o rí i bí ó tí ń lọ ṣe àgbèrè lórí gbogbo òkè ati lábẹ́ gbogbo igi tútù? Mo rò pé yóo pada tọ̀ mí wá, lẹ́yìn tí ó bá ṣe àgbèrè rẹ̀ tán ni; ṣugbọn kò pada; Juda arabinrin rẹ̀, alaiṣootọ sì rí i, ó mọ̀ pé nítorí ìwà àgbèrè Israẹli, alaiṣootọ, ni mo ṣe lé e jáde, tí mo sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Sibẹsibẹ Juda tí òun pàápàá jẹ́ alaiṣootọ, kò bẹ̀rù, òun náà lọ ṣe àgbèrè. Nítorí pé ìwà àgbèrè jẹ́ nǹkan kékeré lójú rẹ̀, ó ṣe àgbèrè pẹlu òkúta ati igi ó sì ba ilẹ̀ náà jẹ́. Sibẹsibẹ, lẹ́yìn gbogbo èyí, Juda arabinrin rẹ̀, ọ̀dàlẹ̀, kò fi tọkàntọkàn pada tọ̀ mí wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ojú ayé ni wọ́n ń ṣe. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” Lẹ́yìn náà OLUWA sọ fún mi pé, “Israẹli jẹ̀bi, aiṣootọ, ṣugbọn kò tíì tó ti Juda, ọ̀dàlẹ̀. Lọ kéde ọ̀rọ̀ yìí sí ìhà àríwá, kí o wí pé: ‘Yipada ìwọ Israẹli alaiṣootọ. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N kò ní bínú sí ọ, nítorí aláàánú ni mí. N kò ní máa bínú lọ títí lae. Ṣá ti gbà pé o jẹ̀bi, ati pé o ti ṣọ̀tẹ̀ sí èmi OLUWA Ọlọrun rẹ. O ti fi ògo rẹ wọ́lẹ̀ fún àwọn àjèjì oriṣa, lábẹ́ gbogbo igi tútù; o kò sì gbọ́ràn sí mi lẹ́nu. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ “Ẹ yipada, ẹ̀yin alaiṣootọ ọmọ, nítorí èmi ni Oluwa yín. N óo yan ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu yín láti inú ìlú kọ̀ọ̀kan, n óo mú meji meji láti inú agbo ilé kọ̀ọ̀kan, n óo sì ko yín wá sí Sioni. N óo fun yín ní àwọn olùṣọ́ aguntan tí ó wù mí, tí yóo fi ìmọ̀ ati òye bọ yín. Nígbà tí ẹ bá pọ̀ síi ní ilẹ̀ náà, ẹ kò ní sọ̀rọ̀ nípa Àpótí Majẹmu OLUWA mọ́, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò ní sọ si yín lọ́kàn, ẹ kò ní ranti rẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn yín kò ní fà sí i mọ́, ẹ kò sì ní ṣe òmíràn mọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀ Ìtẹ́ OLUWA ni wọ́n óo máa pe Jerusalẹmu nígbà náà. Gbogbo orílẹ̀-èdè yóo parapọ̀ wá sibẹ, níwájú èmi OLUWA, ní Jerusalẹmu, wọn kò ní fi oríkunkun tẹ̀ sí ìmọ̀ burúkú ọkàn wọn mọ́. Nígbà tí àkókò bá tó, àwọn ará ilé Juda yóo tọ àwọn ará ilé Israẹli lọ, wọn yóo sì jọ pada láti ilẹ̀ ìhà àríwá, wọn yóo wá sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín tí wọ́n jogún.” OLUWA ní, “Israẹli, mo fẹ́ fi ọ́ ṣe ọ̀kan ninu àwọn ọmọ mi, tí n óo sì fún ọ ní ilẹ̀ tí ó dára, kí n sì fún ọ ní ogún tí ó dára jù, láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù. Mo sì rò pé o óo máa pè mí ní baba rẹ, ati pé o kò ní pada kúrò lẹ́yìn mi. Dájúdájú bí obinrin alaiṣootọ tíí fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni o ti ṣe alaiṣootọ sí mi, ìwọ Israẹli. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” A gbọ́ ohùn kan lórí àwọn òkè gíga, ẹkún ati ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọkunrin Israẹli ni. Nítorí wọ́n ti yapa kúrò lójú ọ̀nà wọn; wọ́n ti gbàgbé OLUWA Ọlọrun wọn. Ẹ yipada, ẹ̀yin alaiṣootọ ọmọ, n óo mú aiṣootọ yín kúrò. “Wò wá! A wá sọ́dọ̀ rẹ, nítorí ìwọ ni OLUWA Ọlọrun wa. Nítòótọ́, ẹ̀tàn ni àwọn òkè, ati gbogbo ohun tí wọn ń lọ ṣe níbẹ̀; dájúdájú lọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun wa ni ìgbàlà Israẹli wà. Ṣugbọn láti ìgbà èwe wa ni ohun ìtìjú yìí ti pa gbogbo ohun tí àwọn baba ńlá wa ṣiṣẹ́ fún run: ẹran ọ̀sìn wọn, ati agbo mààlúù wọn, àwọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin. Ẹ jẹ́ kí á dojúbolẹ̀ kí ìtìjú wa sì bò wá, nítorí pé a ti ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun wa; àtàwa, àtàwọn baba ńlá wa, a kò gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun wa, láti ìgbà èwe wa títí di òní.” OLUWA ní, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, bí ẹ bá fẹ́ yipada, ọ̀dọ̀ mi ni kí ẹ pada sí. Mo kórìíra ìbọ̀rìṣà; nítorí náà bí ẹ bá jáwọ́ ninu rẹ̀, tí ẹ kò bá ṣìnà kiri mọ́, tí ẹ bá ń búra pẹlu òtítọ́ pé, ‘Bí OLUWA ti wà láàyè,’ lórí ẹ̀tọ́ ati òdodo, àwọn orílẹ̀-èdè yòókù yóo máa fi orúkọ mi súre fún ara wọn, wọn yóo sì máa ṣògo ninu mi.” Nítorí pé OLUWA sọ fún àwọn ará Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu pé, “Ẹ tún oko yín tí ẹ ti patì tẹ́lẹ̀ kọ, ẹ má sì gbin èso sáàrin ẹ̀gún. Ẹ kọ ara yín ní ilà abẹ́ fún OLUWA, kí ẹ sì kọ ara yín ní ilà ọkàn, ẹ̀yin ará Juda ati ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu; kí ibinu mi má baà dé, bí iná tí ó ń jó tí kò sí ẹni tí ó lè pa á, nítorí iṣẹ́ ibi yín.” Ẹ sọ ọ́ ní Juda, ẹ sì kéde rẹ̀ láàrin Jerusalẹmu pé, “Ẹ fọn fèrè káàkiri ilẹ̀ náà, kí ẹ sì kígbe sókè pé, ‘Ẹ kó ara yín jọ kí á lọ sí àwọn ìlú olódi.’ Ẹ gbé àsíá sókè sí Sioni, pé kí wọn sá àsálà, kí wọn má ṣe dúró, nítorí mò ń mú ibi ati ìparun ńlá bọ̀ láti ìhà àríwá. Kinniun kan ti jáde lọ láti inú igbó tí ó wà; ọ̀kan ninu àwọn tí wọ́n máa ń run àwọn orílẹ̀-èdè ti gbéra; ó ti jáde kúrò ní ipò rẹ̀, láti sọ ilẹ̀ yín di ahoro. Yóo pa àwọn ìlú yín run, kò sì ní sí eniyan ninu wọn mọ́. Nítorí èyí, ẹ fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora, ẹ sọkún kí ẹ máa ké tẹ̀dùntẹ̀dùn, nítorí ìrúnú gbígbóná OLUWA kò tíì yipada kúrò lọ́dọ̀ wa.” OLUWA ní, “Tó bá di ìgbà náà, ojora yóo mú ọba ati àwọn ìjòyè, àwọn alufaa yóo dààmú, ẹnu yóo ya àwọn wolii.” Mo bá dáhùn pé, “Háà, OLUWA Ọlọrun, àṣé ò ń tan àwọn eniyan wọnyi, ati àwọn ará Jerusalẹmu ni, nígbà tí o sọ fún wọn pé, yóo dára fún wọn; àṣé idà ti dé ọrùn wọn!” A óo wí fún àwọn eniyan yìí, ati àwọn ará Jerusalẹmu ní ìgbà náà pé afẹ́fẹ́ gbígbóná kan ń fẹ́ bọ̀ láti orí àwọn òkè, ninu pápá, ó ń fẹ́ bọ̀ sọ́dọ̀ àwọn eniyan mi; kì í ṣe afẹ́fẹ́ lásán tíí fẹ́ pàǹtí ati ìdọ̀tí dànù. Ìjì tí yóo ti ọ̀dọ̀ mi wá yóo le jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nisinsinyii èmi ni mò ń fi ọ̀rọ̀ mi dá wọn lẹ́jọ́. Ẹ wò ó! Ó ń bọ̀ bí ìkùukùu, kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ dàbí ìjì. Àwọn ẹṣin rẹ̀ yára ju àṣá lọ. A gbé, nítorí ìparun dé bá wa. Ìwọ Jerusalẹmu, fọ ibi dànù kúrò lọ́kàn rẹ, kí á lè gbà ọ́ là. Yóo ti pẹ́ tó tí èrò burúkú yóo fi máa wà lọ́kàn rẹ? Nítorí a gbọ́ ohùn kan láti ilẹ̀ Dani, tí ń kéde ibi láti òkè Efuraimu. Ẹ kìlọ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè pé ó ń bọ̀, kéde fún Jerusalẹmu pé, àwọn ológun tí ń dó ti ìlú ń bọ̀, láti ilẹ̀ òkèèrè. Wọ́n ń kọ lálá sí àwọn ìlú Juda. Wọ́n yí i ká bí àwọn tí ó ń ṣọ́ oko, nítorí pé ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí OLUWA. OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. Ìrìn ẹsẹ̀ rẹ ati ìwà rẹ ni ó mú kí àwọn nǹkan wọnyi dé bá ọ. Ìjìyà rẹ nìyí, ó sì korò; ó ti dé oókan àyà rẹ. Oró ò! Oró ò! Mò ń jẹ̀rora! Àyà mi ò! Àyà mi ń lù kìkìkì, n kò sì lè dákẹ́; nítorí mo gbọ́ ìró fèrè ogun, ati ariwo ogun. Àjálù ń ṣubú lu àjálù, gbogbo ilẹ̀ ti parun. Lójijì àgọ́ mi wó lulẹ̀, aṣọ títa mi sì fàya ní ìṣẹ́jú kan. Yóo ti pẹ́ tó tí n óo máa wo àsíá ogun, tí n óo sì máa gbọ́ fèrè ogun? OLUWA ní, “Nítorí pé àwọn eniyan mi gọ̀, wọn kò mọ̀ mí. Òmùgọ̀ ọmọ ni wọ́n; wọn kò ní òye. Ọgbọ́n àtiṣe ibi kún inú wọn: ṣugbọn wọn kò mọ rere ṣe.” Mo bojú wo ilé ayé, ilé ayé ṣófo, ó rí júujùu; mo ṣíjú wo ojú ọ̀run, kò sí ìmọ́lẹ̀ níbẹ̀. Mo wo àwọn òkè ńlá, wọ́n ń mì tìtì, gbogbo òkè kéékèèké ń sún lọ síhìn-ín sọ́hùn-ún. Mo wò yíká, n kò rí ẹnìkan, gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ti fò sálọ. Mo wò yíká, mo rí i pé gbogbo ilẹ̀ ọlọ́ràá ti di aṣálẹ̀, gbogbo ìlú sì ti di òkítì àlàpà níwájú OLUWA, nítorí ibinu ńlá rẹ̀. Nítorí OLUWA ti sọ pé, gbogbo ilẹ̀ náà yóo di ahoro; sibẹ òpin kò ní tíì dé. Nítorí èyí, ilẹ̀ yóo ṣọ̀fọ̀, ojú ọ̀run yóo sì ṣókùnkùn. Nítorí pé ó ti sọ bẹ́ẹ̀, ó ti rò ó dáradára, kò tíì jáwọ́ ninu rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní yipada. Nígbà tí wọ́n gbọ́ ariwo àwọn ẹlẹ́ṣin ati ti àwọn tafàtafà, gbogbo ìlú sá jáde fún ààbò. Wọ́n sá wọ inú igbó lọ, wọ́n gun orí òkè lọ sinu pàlàpálá òkúta; gbogbo ìlú sì di ahoro. Ìwọ tí o ti di ahoro, kí ni èrò rẹ tí o fi wọ aṣọ elése àlùkò? Tí o wa nǹkan ọ̀ṣọ́ wúrà sára? Tí o tọ́ ojú? Tí o tọ́ ètè? Asán ni gbogbo ọ̀ṣọ́ tí o ṣe, àwọn olólùfẹ́ rẹ kò kà ọ́ sí, ọ̀nà ati gba ẹ̀mí rẹ ni wọ́n ń wá. Nítorí mo gbọ́ igbe kan, tí ó dàbí igbe obinrin tí ó ń rọbí, ó ń kérora bí aboyún tí ó ń rọbí alákọ̀ọ́bí. Mo gbọ́ igbe Jerusalẹmu tí ń pọ̀ọ̀kà ikú, tí ó na ọwọ́ rẹ̀ síta, tí ń ké pé, “Mo gbé! Mò ń kú lọ, lọ́wọ́ àwọn apànìyàn!” Máa sáré lọ, sáré bọ̀ ní àwọn òpópónà Jerusalẹmu, wò yíká, kí o sì ṣàkíyèsí rẹ̀! Wo àwọn gbàgede rẹ̀, bóyá o óo rí ẹnìkan, tí ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo, tí ó sì ń fẹ́ òtítọ́, tí mo fi lè torí rẹ̀ dáríjì Jerusalẹmu. Lóòótọ́ ni wọ́n ń fi orúkọ mi búra pé, “Bí OLUWA tí ń bẹ,” sibẹ èké ni ìbúra wọn. OLUWA, ṣebí òtítọ́ ni ò ń fẹ́? Ò ń nà wọ́n ní pàṣán, ṣugbọn kò dùn wọ́n, o tẹ̀ wọ́n ní àtẹ̀rẹ́, ṣugbọn wọn kò gbọ́ ìbáwí. Ojú wọn ti dá, ó le koko, wọ́n kọ̀, wọn kò ronupiwada. Nígbà náà ní mo wí lọ́kàn ara mi pé, “Àwọn aláìní nìkan nìwọ̀nyí, wọn kò gbọ́n; nítorí wọn kò mọ ọ̀nà OLUWA, ati òfin Ọlọrun wọn. N óo lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan pataki pataki, n óo sì bá wọn sọ̀rọ̀; nítorí àwọn mọ ọ̀nà OLUWA, ati òfin Ọlọrun wọn.” Ṣugbọn gbogbo wọn náà ni wọ́n ti fa àjàgà wọn dá, tí wọ́n sì ti kọ àṣẹ ati àkóso OLUWA. Nítorí náà, kinniun inú igbó ni yóo wá kì wọ́n mọ́lẹ̀. Ìkookò inú aṣálẹ̀ ni yóo wá jẹ wọ́n run. Àmọ̀tẹ́kùn yóo ba dè wọ́n ní àwọn ìlú wọn, tí ẹnikẹ́ni bá jáde ní ìlú, yóo fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ wọn pọ̀, nígbà pupọ ni wọ́n sì ti yipada kúrò ní ọ̀nà Ọlọrun. OLUWA bi Israẹli pé, “Báwo ni mo ṣe lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jìn ọ́? Àwọn ọmọ rẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n sì ti ń fi àwọn ohun tí kì í ṣe ọlọrun búra. Nígbà tí mo bọ́ wọn ní àbọ́yó tán, wọ́n ṣe àgbèrè, wọ́n dà lọ sí ilé àwọn alágbèrè. Wọ́n dàbí akọ ẹṣin tí a kò tẹ̀ lọ́dàá, tí ó yó, olukuluku wọn ń lé aya aládùúgbò rẹ̀ kiri. Ṣé n kò wá ní jẹ wọ́n níyà fún àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe wọnyi? Àbí n kò ní gbẹ̀san ara mi lára irú orílẹ̀-èdè yìí? Kọjá lọ láàrin ọgbà àjàrà rẹ̀ ní poro ní poro, kí o sì pa á run, ṣugbọn má ṣe pa gbogbo rẹ̀ run tán. Gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò, nítorí pé wọn kì í ṣe ti OLUWA. Nítorí pé ilé Israẹli ati ilé Juda ti ṣe alaiṣootọ sí mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” Àwọn eniyan yìí ti sọ ọ̀rọ̀ èké nípa OLUWA, wọ́n ní, “OLUWA kọ́! Kò ní ṣe nǹkankan; ibi kankan kò ní dé bá wa, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní rí ogun tabi ìyàn.” Àwọn wolii yóo di àgbá òfo; nítorí kò sí ọ̀rọ̀ OLUWA ninu wọn. Bí wọ́n ti wí ni ọ̀rọ̀ yóo rí fún wọn. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní, “Nítorí ohun tí wọ́n sọ yìí, wò ó, n óo jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi di iná lẹ́nu rẹ. N óo sì jẹ́ kí àwọn eniyan wọnyi dàbí igi, iná yóo sì jó wọn run. Ẹ wò ó, ẹ̀yin ọmọ ilé Israẹli, mò ń mú orílẹ̀-èdè kan bọ̀ wá ba yín, láti ilẹ̀ òkèèrè, tí yóo ba yín jà. Láti ayé àtijọ́ ni orílẹ̀-èdè ọ̀hún ti wà, orílẹ̀-èdè alágbára ni. Ẹ kò gbọ́ èdè wọn, ẹ kò sì ní mọ ohun tí wọ́n ń sọ. Apó ọfà wọn dàbí isà òkú tó yanu sílẹ̀, alágbára jagunjagun ni gbogbo wọn. Wọn yóo jẹ yín ní oúnjẹ, wọn yóo sì kó gbogbo ìkórè oko yín lọ, wọn yóo run àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin. Wọn yóo run ẹran ọ̀sìn yín, ati àwọn mààlúù yín. Wọn yóo run èso ọgbà àjàrà yín, ati igi ọ̀pọ̀tọ́ yín. Idà ni wọn yóo fi pa àwọn ìlú olódi yín tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé run.” OLUWA ní, “Ṣugbọn sibẹ, ní gbogbo àkókò yìí, n kò ní pa yín run patapata, nígbà tí àwọn eniyan bá bèèrè pé, ‘Kí ló dé tí OLUWA Ọlọrun wa fi ṣe gbogbo nǹkan wọnyi sí wa?’ Ẹ óo le dá wọn lóhùn pé bí ẹ ṣe kọ èmi OLUWA sílẹ̀, tí ẹ sì ń bọ oriṣa àjèjì ní ilẹ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe sin àwọn àjèjì ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiyín.” OLUWA ní, “Kéde rẹ̀ ní ilẹ̀ Jakọbu, sì ṣe ìfilọ̀ rẹ̀ ní ilẹ̀ Juda: Ẹ wá gbọ́, ẹ̀yin òmùgọ̀, aláìlọ́gbọ́n, ẹ̀yin tí ẹ lójú, ṣugbọn tí ẹ kò ríran; ẹ létí, ṣugbọn tí ẹ kò gbọ́ràn. Ẹ̀rù mi kò tilẹ̀ bà yín? Èmi OLUWA ni mò ń bi yín léèrè. Ẹ wà níwájú mi ẹ kò máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀. Èmi tí mo fi iyanrìn pààlà fún omi òkun, tí òkun kò sì gbọdọ̀ rékọjá rẹ̀ títí ayé! Bí ó tilẹ̀ ń ru sókè, kò lágbára kan, kí ìgbì rẹ̀ máa hó yaya, kò lè kọjá ààlà náà. Ṣugbọn ọkàn ẹ̀yin eniyan wọnyi le, ọlọ̀tẹ̀ sì ni yín. Ẹ ti yapa, ẹ sì ti ṣáko lọ. Ẹ kò sì rò ó lọ́kàn yín, kí ẹ wí pé: ‘Ẹ jẹ́ kí á bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun wa, tí ó ń fún wa ní òjò lákòókò rẹ̀, ati òjò àkọ́rọ̀ ati àrọ̀kẹ́yìn; OLUWA tí ó ń bá wa mú ọjọ́ ìkórè lọ́wọ́, tí kì í jẹ́ kí àsìkò ìkórè ó yẹ̀.’ Àìdára yín ti yí ìgbà wọnyi pada, ẹ̀ṣẹ̀ yín ti dínà ohun rere fun yín. “Àwọn eniyan burúkú wà láàrin àwọn eniyan mi, wọ́n ń dọdẹ eniyan bí ẹni dọdẹ ẹyẹ, wọ́n dẹ tàkúté, wọ́n fi ń mú eniyan. Ilé wọn kún fún ìwà ọ̀dàlẹ̀, bíi kùùkú tí ó kún fún ẹyẹ. Nítorí èyí, wọ́n di eniyan ńlá, wọ́n di olówó, wọ́n sanra, ara wọn sì ń dán. Ṣugbọn iṣẹ́ ibi wọn kò ní ààlà. Wọn kìí dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ fún aláìníbaba, kí ó lè rí ẹ̀tọ́ rẹ̀ gbà; wọn kò sì jẹ́ gbèjà aláìní, kí wọ́n bá a dáàbò bo ẹ̀tọ́ rẹ̀ nílé ẹjọ́. Ṣé n kò wá ní jẹ wọ́n níyà fún àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe wọnyi? Kí n má gbẹ̀san ara mi, lára irú orílẹ̀-èdè yìí? Nǹkan burúkú tó yani lẹ́nu, ní ń ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ náà: Àwọn wolii ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké, àwọn alufaa ń sọ ọ̀rọ̀ èké àwọn wolii di òfin, àwọn eniyan mi sì fẹ́ ẹ bẹ́ẹ̀. Ṣugbọn kí ni wọ́n óo ṣe nígbà tí òpin bá dé?” Ẹ̀yin ọmọ Bẹnjamini, ẹ sá àsálà! Ẹ sá kúrò ní Jerusalẹmu. Ẹ fọn fèrè ogun ní Tekoa, kí ẹ ṣe ìkìlọ̀ fún wọn ní Beti Hakikeremu, nítorí pé nǹkan burúkú ati ìparun ńlá ń bọ̀ láti ìhà àríwá. Jerusalẹmu, Ìlú Sioni dára, ó sì lẹ́wà, ṣugbọn n óo pa á run. Àwọn ọba ati àwọn ọmọ ogun wọn yóo kọlù ú, wọn yóo pa àgọ́ yí i ká, ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan yóo pàgọ́ sí ibi tí ó wù ú. Wọn yóo sì wí pé, “Ẹ múra kí á bá a jagun; ẹ dìde kí á lè kọlù ú lọ́sàn-án gangan!” Wọn óo tún sọ pé, “A gbé! Nítorí pé ọjọ́ ti lọ, ilẹ̀ sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣú! Ẹ dìde kí á lè kọlù ú, lóru; kí á wó àwọn ilé ìṣọ́ rẹ̀ lulẹ̀!” Nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ti pàṣẹ fún àwọn ọ̀tá pé: “Ẹ gé àwọn igi tí ó yí Jerusalẹmu ká lulẹ̀; kí ẹ fi mọ òkítì kí ẹ sì dótì í. Dandan ni kí n fi ìyà jẹ ìlú náà, nítorí kìkì ìwà ìninilára ló kún inú rẹ̀. Bí omi ṣé ń sun jáde ninu kànga, bẹ́ẹ̀ ni ibi ń sun ní Jerusalẹmu. Ìròyìn ìwà ipá ati ti jàgídíjàgan ń kọlura wọn ninu rẹ̀, àìsàn ati ìpalára ni à ń rí níbẹ̀ nígbà gbogbo. Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu! Ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ tí mò ń ṣe fun yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi pẹlu yín óo pínyà, n óo sì sọ Jerusalẹmu di ahoro, ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé ibẹ̀ mọ́.” OLUWA àwọn ọmọ ogun ní: “Ẹ ṣa àwọn ọmọ Israẹli yòókù jọ, bí ìgbà tí eniyan bá ń ṣa èso àjàrà tókù lẹ́yìn ìkórè. Tún dá ọwọ́ pada sẹ́yìn, kí o fi wọ́ ara àwọn ẹ̀ka, bí ẹni tí ń ká èso àjàrà.” Mo ní, “Ta ni kí n bá sọ̀rọ̀, tí yóo gbọ́? Ta ni kí n kìlọ̀ fún tí yóo gbà? Etí wọn ti di, wọn kò lè gbọ́ràn mọ́. Ọ̀rọ̀ OLUWA ń rùn létí wọn, wọn kò fẹ́ gbọ́ mọ́. Ibinu ìwọ OLUWA mú kí inú mi máa ru, ara mi kò sì gbà á mọ́.” OLUWA bá sọ fún mi pé, “Tú ibinu mi dà sórí àwọn ọmọde ní ìta gbangba, ati àwọn ọdọmọkunrin níbi tí wọ́n péjọ sí. Ogun yóo kó wọn, tọkọtaya, àtàwọn àgbàlagbà àtàwọn arúgbó kùjọ́kùjọ́. Ilé wọn yóo di ilé onílé, oko wọn, ati àwọn aya wọn pẹlu, yóo di ti ẹni ẹlẹ́ni. Nítorí pé n óo na ọwọ́ ibinu mi sí àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA ní, “Láti orí àwọn mẹ̀kúnnù títí dé orí àwọn eniyan pataki pataki, gbogbo wọn ni wọ́n fẹ́ràn èrè àjẹjù; láti orí àwọn wolii títí dé orí àwọn alufaa, èké ni gbogbo wọn. Wọn kò wẹ egbò àwọn eniyan mi jiná, wọ́n ń kígbe pé: ‘Alaafia ni, alaafia ni’, nígbà tí kò sí alaafia. Ǹjẹ́ ojú a tilẹ̀ máa tì wọ́n nígbà tí wọ́n bá ń hu ìwà ìbàjẹ́? Rárá o, ojú kì í tì wọ́n; nítorí pé wọn kò lójútì. Nítorí náà, àwọn náà óo ṣubú nígbà tí àwọn yòókù bá ṣubú, a ó bì wọ́n ṣubú nígbà tí mo bá ń jẹ wọ́n níyà, Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA ní, “Ẹ lọ dúró ní oríta kí ẹ wo òréré, ẹ bèèrè àwọn ọ̀nà àtijọ́, níbi tí ọ̀nà dáradára wà, kí ẹ sì máa tọ̀ ọ́. Kí ẹ lè ní ìsinmi.” Ṣugbọn wọ́n kọ̀, wọ́n ní, “A kò ní tọ ọ̀nà náà.” Mo fi àwọn aṣọ́nà ṣọ́nà nítorí yín. Mo wí fún wọn pé, “Ẹ máa dẹtí sílẹ̀ sí fèrè ogun!” Ṣugbọn wọ́n ní, “A kò ní dẹtí sílẹ̀.” OLUWA ní, “Nítorí náà, ẹ gbọ́, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, kí ẹ̀yin eniyan sì mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí wọn. Gbọ́! Ìwọ ilẹ̀; n óo fa ibi lé àwọn eniyan wọnyi lórí, wọn óo jèrè èso ìwà burúkú wọn; nítorí pé wọn kò fetí sí ọ̀rọ̀ mi, wọ́n sì ti tàpá sí òfin mi. Kí ni anfaani turari, tí wọn mú wá fún mi láti Ṣeba, tabi ti ọ̀pá turari olóòórùn dídùn tí ó ti ilẹ̀ òkèèrè wá? N kò tẹ́wọ́ gba ọrẹ ẹbọ sísun tí ẹ mú wá siwaju mi, bẹ́ẹ̀ ni ẹbọ yín kò dùn mọ́ mi. Nítorí náà, n óo gbé ohun ìdínà sọ́nà fún àwọn eniyan wọnyi, wọn óo sì fẹsẹ̀ kọ; ati baba, àtọmọ wọn, àtaládùúgbò, àtọ̀rẹ́, gbogbo wọn ni yóo parun.” OLUWA ní, “Wò ó, àwọn eniyan kan ń bọ̀ láti ilẹ̀ àríwá, orílẹ̀-èdè ńlá ń gbéra bọ̀ láti òpin ayé. Wọ́n ń kó ọrun ati ọ̀kọ̀ bọ̀, ìkà ni wọ́n, wọn kò sì lójú àánú. Ìró wọn dàbí híhó omi òkun, bí wọ́n ti ń gun ẹṣin bọ̀. Wọ́n tò bí àwọn tí ń lọ sójú ogun, wọ́n dótì ọ́, ìwọ Jerusalẹmu!” A gbúròó wọn, ọwọ́ wa rọ; ìdààmú dé bá wa, bí ìrora obinrin tí ó ń rọbí. Ẹ má lọ sinu oko, ẹ má sì ṣe rìn lójú ọ̀nà náà, nítorí ọ̀tá mú idà lọ́wọ́, ìdágìrì sì wà káàkiri. Ẹ̀yin eniyan mi, ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí ẹ máa yí ninu eérú; ẹ máa ṣọ̀fọ̀, bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ kanṣoṣo; kí ẹ sì máa sunkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, nítorí pé lójijì ni àwọn apanirun yóo bò yín. Mo ti fi ọ́ ṣe ẹni tí yóo máa dán àwọn eniyan mi wò, o óo máa dán wọn wò bí ẹni dán irin wò, o óo gbìyànjú láti mọ ọ̀nà wọn, kí o lè yẹ ọ̀nà wọn wò, kí o sì mọ̀ ọ́n. Ọlọ̀tẹ̀, aláìgbọràn ni gbogbo wọn, wọn á máa sọ̀rọ̀ eniyan lẹ́yìn. Wọ́n dàbí idẹ àdàlú mọ́ irin, àmúlùmálà ni gbogbo wọn. Lóòótọ́ à ń fi ẹwìrì fẹ́ iná, òjé sì ń yọ́ lórí iná; ṣugbọn alágbẹ̀dẹ ń yọ́ irin lásán ni, kò mú ìbàjẹ́ ara rẹ̀ kúrò. Ìdọ̀tí fadaka tí a kọ̀ tì ni wọ́n, nítorí pé OLUWA ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀. OLUWA rán Jeremaya níṣẹ́, ó ní kí Jeremaya dúró sí ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA, kí ó sì kéde pé: “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, gbogbo ẹ̀yin ará Juda tí ń gba ẹnu ọ̀nà wọnyi wọlé láti sin OLUWA. OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní: ‘Ẹ tún ìrìn ẹsẹ̀ yín ati iṣẹ́ ọwọ́ yín ṣe, kí n lè jẹ́ kí ẹ máa gbé ìhín. Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn yìí pé: “Tẹmpili OLUWA nìyí, kò séwu, tẹmpili OLUWA nìyí.” “ ‘Bí ẹ bá tún ìrìn ẹsẹ̀ yín ati iṣẹ́ ọwọ́ yín ṣe nítòótọ́, tí ẹ bá ń dá ẹjọ́ òtítọ́, tí ẹ kò bá fi ìyà jẹ àwọn àlejò, ati àwọn aláìníbaba, tabi àwọn opó, tabi kí ẹ máa ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ibí yìí, tí ẹ kò sì máa bọ oriṣa káàkiri, kí ẹ fi kó bá ara yín, n óo jẹ́ kí ẹ máa gbé ibí yìí títí lae, lórí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín láti ìgbà laelae. “ ‘Ẹ wò ó! Ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn tí kò lè mú èrè wá ni ẹ gbójú lé. Ṣé ẹ fẹ́ máa jalè, kí ẹ máa pa eniyan, kí ẹ máa ṣe àgbèrè, kí ẹ máa búra èké, kí ẹ máa sun turari sí oriṣa Baali, kí ẹ máa bọ àwọn oriṣa tí ẹ kò mọ̀ káàkiri; kí ẹ sì tún máa wá jọ́sìn níwájú mi ninu ilé yìí, ilé tí à ń fi orúkọ mi pè; kí ẹ máa wí pé, “OLUWA ti gbà wá là;” kí ẹ sì tún pada lọ máa ṣe gbogbo àwọn nǹkan ìríra tí ẹ tí ń ṣe? Ṣé lójú tiyín, ilé yìí, tí à ń fi orúkọ mi pè, ó ti wá di ibi ìsápamọ́ sí fún àwọn olè? Mo ti ri yín; èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Nisinsinyii, ẹ lọ sí ilé mi ní Ṣilo, níbi ìjọ́sìn mi àkọ́kọ́, kí ẹ sì wo ohun tí mo ṣe sí i, nítorí ìwà burúkú Israẹli, àwọn eniyan mi. Nisinsinyii, nítorí gbogbo ohun tí ẹ̀ ń ṣe wọnyi, tí mo sì ń ba yín sọ̀rọ̀ lemọ́lemọ́, tí ẹ kò gbọ́, tí mo pè yín, tí ẹ kò dáhùn, bí mo ti ṣe sí Ṣilo ni n óo ṣe ilé tí à ń fi orúkọ mi pè, tí ẹ gbójú lé; ati ilẹ̀ tí mo fún ẹ̀yin ati àwọn baba ńlá yín. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo le yín kúrò níwájú mi, bí mo ti lé àwọn ọmọ Efuraimu, tí wọ́n jẹ́ arakunrin yín dànù.’ ” OLUWA ní, “Ìwọ Jeremaya ní tìrẹ, má bẹ̀bẹ̀ fún àwọn eniyan wọnyi, má sọkún nítorí wọn, tabi kí o gbadura fún wọn. Má sì bẹ̀ mí nítorí wọn, nítorí n kò ní gbọ́. Ṣé o kò rí àwọn ohun tí wọn ń ṣe ninu àwọn ìlú Juda ati ní ìgboro Jerusalẹmu ni? Àwọn ọmọ ń kó igi jọ, àwọn baba wọn ń dá iná, àwọn obinrin ń po ìyẹ̀fun láti fi ṣe àkàrà fún Ayaba Ọ̀run. Wọ́n sì ń ta ọtí sílẹ̀ fún àwọn oriṣa láti mú mi bínú. Ṣé èmi ni wọ́n ń mú bínú? Kì í ṣe pé ara wọn ni wọ́n ń ṣe, tí wọ́n sì ń dójú ti ara wọn? Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun óo tú ibinu gbígbóná mi sórí ibí yìí, n óo bínú sí eniyan ati ẹranko, ati igi oko ati èso ilẹ̀. Ibinu mi óo jó wọn run bí iná, kò sì ní ṣe é pa. “Ẹ da ẹbọ sísun yín pọ̀ mọ́ ẹran tí ẹ fi rúbọ, kí ẹ lè rí ẹran jẹ; Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Nítorí ní ọjọ́ tí mo kó àwọn baba yín jáde ní ilẹ̀ Ijipti, n kò bá wọn sọ̀rọ̀ ẹbọ sísun tabi ẹbọ rírú, bẹ́ẹ̀ ni n kò pàṣẹ rẹ̀ fún wọn. Àṣẹ tí mo pa fún wọn ni pé kí wọn gbọ́ràn sí mi lẹ́nu. Mo ní n óo máa jẹ́ Ọlọrun wọn, àwọn náà óo sì máa jẹ́ eniyan mi; mo ní kí wọn máa tọ ọ̀nà tí mo bá pa láṣẹ fún wọn, kí ó lè dára fún wọn. Ṣugbọn wọn kò gbọ́ràn, wọn kò sì tẹ́tí sí mi. Wọ́n ń tẹ̀lé ìmọ̀ ara wọn, wọ́n ń ṣe oríkunkun, dípò kí wọ́n máa lọ siwaju, ẹ̀yìn ni wọ́n ń pada sí. Láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá yín ti jáde ní ilẹ̀ Ijipti títí di òní, lojoojumọ ni mò ń rán àwọn wolii iranṣẹ mi sí wọn léraléra. Sibẹ wọn kò gbọ́ tèmi, wọn kò tẹ́tí sí mi. Kàkà bẹ́ẹ̀, oríkunkun ni wọ́n ń ṣe. Iṣẹ́ burúkú wọn ju ti àwọn baba ńlá wọn lọ. “Gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi ni o óo sọ fún wọn, ṣugbọn wọn kò ní gbọ́. O óo pè wọ́n, ṣugbọn wọn kò ní dá ọ lóhùn. O óo sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin ni orílẹ̀-èdè tí kò gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ̀, tí kò sì gbọ́ ìbáwí. Òtítọ́ kò sí mọ́ ninu ìṣe yín, bẹ́ẹ̀ ni, kò sì sí ninu ọ̀rọ̀ ẹnu yín.’ “Ẹ gé irun orí yín dànù, ẹ lọ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn lórí òkè, nítorí OLUWA ti kọ ìran yín sílẹ̀, ó ti fi ibinu ta ìran yín nù. “Àwọn ọmọ Juda ti ṣe nǹkan burúkú. Wọ́n gbé ère wọn kalẹ̀ ninu ilé tí à ń fi orúkọ mi pè, wọ́n sì ti sọ ọ́ di aláìmọ́. Wọ́n kọ́ pẹpẹ Tofeti ní àfonífojì Hinomu, wọ́n ń sun àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin wọn níná níbẹ̀. N kò pa irú àṣẹ bẹ́ẹ̀ fún wọn; irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò tilẹ̀ fi ìgbà kan sí lọ́kàn mi. Nítorí náà nígbà tó bá yá, a kò ní pè é ní Tofeti tabi àfonífojì ọmọ Hinomu mọ́, àfonífojì ìpànìyàn ni a óo sì máa pè é. Tofeti ni wọn yóo sì máa sin òkú sí nígbà tí kò bá sí ààyè ní ibòmíràn mọ́. Òkú àwọn eniyan yìí yóo di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ati fún àwọn ẹranko, kò sì ní sí ẹni tí yóo lé wọn. N óo fi òpin sí ẹ̀rín ati ìró ayọ̀ ní Jerusalẹmu, a kò sì ní gbọ́ ohùn ọkọ iyawo ati ohùn iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé níbẹ̀ mọ́; nítorí pé n óo sọ ilẹ̀ náà di ahoro. “Tó bá di ìgbà náà, wọn yóo kó egungun àwọn ọba Juda jáde kúrò ninu ibojì wọn, ati egungun àwọn ìjòyè ibẹ̀; ati ti àwọn alufaa, ati ti àwọn wolii, ati ti àwọn ará Jerusalẹmu. Wọn óo fọ́n wọn dà sílẹ̀ ninu oòrùn, ati lábẹ́ òṣùpá ati àwọn ìràwọ̀ tí wọ́n ní ìfẹ́ sí, tí wọ́n sì sìn; àwọn ohun tí wọn ń wá kiri, tí wọn ń ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ wọn, tí wọ́n sì ń bọ. A kò ní kó egungun wọn jọ, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní sin wọ́n. Wọn óo dàbí ìgbọ̀nsẹ̀ lórí ilẹ̀. Yóo sàn kí àwọn tí ó bá kù ninu ìran burúkú yìí kú ju kí wọ́n wà láàyè lọ, ní ibikíbi tí mo bá lé wọn lọ. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA ní kí n sọ fún wọn pé, “Ṣé bí eniyan bá ṣubú kì í tún dìde mọ́? Àbí bí eniyan bá ṣìnà, kì í pada mọ́? Kí ló dé tí àwọn eniyan wọnyi fi yipada kúrò lọ́dọ̀ mi, tí wọn ń lọ láì bojúwẹ̀yìn? Ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ni wọ́n sì wawọ́ mọ́; wọ́n kọ̀, wọn kò pada sọ́dọ̀ mi. Mo tẹ́tí sílẹ̀ kí n gbọ́ tiwọn, ṣugbọn wọn kò sọ̀rọ̀ rere. Kò sí ẹni tí ó kẹ́dùn iṣẹ́ ibi rẹ̀, kí ó wí pé, ‘Kí ni mo ṣe yìí?’ Olukuluku tẹ̀ sí ọ̀nà tí ó wù ú, bí ẹṣin tí ń sáré lọ ojú ogun. Ẹyẹ àkọ̀ tí ń fò lójú ọ̀run pàápàá mọ àkókò rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni àdàbà, ati lékèélékèé, ati alápàáǹdẹ̀dẹ̀; wọ́n mọ àkókò tí ó yẹ láti ṣípò pada. Ṣugbọn àwọn eniyan mi kò mọ òfin OLUWA. Báwo ni ẹ ṣe lè wí pé, ‘Ọlọ́gbọ́n ni wá, a sì mọ òfin OLUWA?’ Ṣugbọn àwọn akọ̀wé ti fi gègé irọ́ wọn sọ ọ́ di èké. Ojú yóo ti àwọn ọlọ́gbọ́n: ìdààmú yóo bá wọn, ọwọ́ yóo sì tẹ̀ wọ́n. Wò ó! Wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ OLUWA sílẹ̀, ọgbọ́n wo ni ó kù tí wọ́n gbọ́n? Nítorí náà, n óo fi aya wọn fún ẹlòmíràn, n óo fi oko wọn fún àwọn tí yóo ṣẹgun wọn. Nítorí pé láti orí àwọn mẹ̀kúnnù, títí dé orí àwọn eniyan pataki pataki, gbogbo wọn ni wọ́n ń lépa èrè àjẹjù. Láti orí wolii títí kan alufaa, èké ni gbogbo wọn. Wọn kò wẹ egbò àwọn eniyan mi jinná, wọ́n ń kígbe pé, ‘Alaafia ni, alaafia ni,’ bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí alaafia. Ǹjẹ́ ojú a tilẹ̀ máa tì wọ́n nígbà tí wọ́n bá ń hu ìwà ìbàjẹ́? Rárá o, ojú kì í tì wọ́n, nítorí pé wọn kò lójútì. Nítorí náà àwọn náà óo ṣubú nígbà tí àwọn yòókù bá ṣubú, a óo bì wọ́n ṣubú nígbà tí mo bá ń jẹ wọ́n níyà, OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. “Ní àkókò ìkórè, kò ní sí èso lórí àjàrà, igi ọ̀pọ̀tọ́ kò ní ní èso lórí, àwọn ewé pàápàá yóo gbẹ, ohun tí mo fún wọn yóo di ti ẹlòmíràn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” Àwọn eniyan Ọlọrun bá dáhùn pé, “Kí ló dé tí a fi jókòó jẹ̀kẹ̀tẹ̀? Ẹ jẹ́ kí á kó ara wa jọ, kí á sá lọ sí àwọn ìlú olódi, kí á sì parun sibẹ; nítorí OLUWA Ọlọrun wa ti fi wá lé ìparun lọ́wọ́, ó ti fún wa ní omi tí ó ní májèlé mu, nítorí pé a ti ṣẹ̀ ẹ́. À ń retí alaafia, ṣugbọn ire kankan kò dé. Àkókò ìwòsàn ni à ń retí, ṣugbọn ìpayà ni a rí. Ẹ gbọ́ bí ẹṣin wọn tí ń fọn imú, ní ilẹ̀ Dani; gbogbo ilẹ̀ ń mì tìtì nítorí ìró yíyan ẹṣin wọn. Wọ́n wá run ilẹ̀ náà, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀, ati ìlú ati àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀.” OLUWA ní, “Wò ó! N óo rán ejò sí ààrin yín: paramọ́lẹ̀ tí kò ní gbóògùn; wọn yóo sì bù yín jẹ.” Ìbànújẹ́ mi pọ̀ kọjá ohun tí ó ṣe é wòsàn, àárẹ̀ mú ọkàn mi. Ẹ gbọ́ igbe àwọn eniyan mi jákèjádò ilẹ̀ náà tí wọn ń bèèrè pé, “Ṣé OLUWA kò sí ní Sioni ni? Tabi ọba rẹ̀ kò sí ninu rẹ̀ ni?” OLUWA, ọba wọn dáhùn pé, “Kí ló dé tí wọn ń fi ère wọn mú mi bínú, pẹlu àwọn oriṣa ilẹ̀ àjèjì tí wọn ń bọ?” Àwọn eniyan ní, “Ìkórè ti parí, àsìkò ẹ̀ẹ̀rùn ti kọjá, sibẹ a kò rí ìgbàlà.” Nítorí ọgbẹ́ àwọn eniyan mi ni ọkàn mi ṣe gbọgbẹ́. Mò ń ṣọ̀fọ̀, ìdààmú sì bá mi. Ṣé kò sí ìwọ̀ra ní Gileadi ni? Àbí kò sí oníwòsàn níbẹ̀? Kí ló dé tí àìsàn àwọn eniyan mi kò sàn? Orí mi ìbá jẹ́ kìkì omi, kí ojú mi sì jẹ́ orísun omijé; tọ̀sán-tòru ni ǹ bá fi máa sọkún, nítorí àwọn eniyan mi tí ogun ti pa. Ìbá ṣe pé mo ní ilé èrò kan ninu aṣálẹ̀, ǹ bá kó àwọn eniyan mi dà sílẹ̀ níbẹ̀, ǹ bá sì kúrò lọ́dọ̀ wọn; nítorí alágbèrè ni gbogbo wọn, ati àgbájọ àwọn alárèékérekè eniyan. Bí ẹni kẹ́ ọrun ni wọ́n kẹ́ ahọ́n wọn, láti máa fọ́n irọ́ jáde bí ẹni ta ọfà; dípò òtítọ́ irọ́ ní ń gbilẹ̀ ní ilẹ̀ náà. OLUWA ní, “Wọ́n ń tinú ibi bọ́ sinu ibi, wọn kò sì mọ̀ èmi OLUWA.” Kí olukuluku ṣọ́ra lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, kí ó má sì gbẹ́kẹ̀lé arakunrin rẹ̀ kankan. Nítorí pé ajinnilẹ́sẹ̀ ni gbogbo arakunrin, a-fọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-ba-tẹni-jẹ́ sì ni gbogbo aládùúgbò. Olukuluku ń tan ọ̀rẹ́ rẹ̀ jẹ, kò sì sí ẹnìkan tí ń sọ òtítọ́. Wọ́n ti kọ́ ahọ́n wọn ní irọ́ pípa; wọ́n dẹ́ṣẹ̀ títí, ó sú wọn, wọn kò sì ronú àtipàwàdà. Ìninilára ń gorí ìninilára, ẹ̀tàn ń gorí ẹ̀tàn, OLUWA ní, “Wọ́n kọ̀ wọn kò mọ̀ mí.” Nítorí náà, ó ní: “Wò ó! N óo fọ̀ wọ́n mọ́, n óo dán wọn wò. Àbí, kí ni kí n tún ṣe fún àwọn eniyan yìí? Ahọ́n wọn dàbí ọfà apanirun, wọ́n ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn. Olukuluku ń sọ̀rọ̀ alaafia jáde lẹ́nu fún aládùúgbò rẹ̀, ṣugbọn ète ikú ni ó ń pa sí i ninu ọkàn rẹ̀. Ṣé n kò wá ní jẹ wọ́n níyà fún àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe wọnyi? Àbí n kò ní gbẹ̀san ara mi lára irú orílẹ̀-èdè yìí?” Mo ní, “Gbé ẹnu sókè kí o sọkún nítorí àwọn òkè ńlá, sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn nítorí àwọn pápá inú aṣálẹ̀, nítorí gbogbo wọn ti di ahoro, láìsí ẹnìkan tí yóo la ààrin wọn kọjá. A kò ní gbọ́ ohùn ẹran ọ̀sìn níbẹ̀. Ati ẹyẹ, ati ẹranko, gbogbo wọn ti sá lọ.” OLUWA ní, “N óo sọ Jerusalẹmu di àlàpà ati ibùgbé ajáko. N óo sọ àwọn ìlú Juda di ahoro ẹnikẹ́ni kò ní gbé inú wọn mọ́. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” Mo bá bèèrè pé, “Ta ni ẹni tí ó gbọ́n, tí òye nǹkan yìí yé? Ta ni OLUWA ti bá sọ̀rọ̀, kí ó kéde rẹ̀? Kí ló dé tí ilẹ̀ náà fi parun, tí ó sì dàbí aṣálẹ̀ tóbẹ́ẹ̀, tí ẹnikẹ́ni kò fi gba ibẹ̀ kọjá?” OLUWA bá dáhùn, ó ní, “Nítorí pé wọ́n kọ òfin tí mo gbékalẹ̀ fún wọn sílẹ̀, wọn kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, wọn kò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ mi, ṣugbọn wọ́n ń fi agídí ṣe ìfẹ́ ọkàn wọn, wọ́n ń bọ àwọn oriṣa Baali, bí àwọn baba wọn ti kọ́ wọn. Nítorí náà, n óo fún wọn ní igi tí ó korò jẹ, n óo sì fún wọn ní omi tí ó ní májèlé mu. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo fọ́n wọn ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn ati àwọn baba ńlá wọn kò mọ̀, n óo sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá yọ idà tẹ̀lé wọn títí tí n óo fi pa wọ́n run.” OLUWA àwọn ọmọ ogun ní: “Ẹ ronú sí ọ̀rọ̀ yìí kí ẹ pe àwọn obinrin tíí máa ń ṣọ̀fọ̀ wá, ẹ ranṣẹ pe àwọn obinrin tí wọ́n mọ ẹkún sun dáradára; kí wọ́n wá kíá, kí wọ́n wá máa sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn lé wa lórí, kí omi sì máa dà lójú wa pòròpòrò. Nítorí a gbọ́ tí ẹkún sọ ní Sioni, wọ́n ń ké pé, ‘A gbé! Ìtìjú ńlá dé bá wa, a níláti kó jáde nílé, nítorí pé àwọn ọ̀tá ti wó ilé wa.’ ” Mo ní, “Ẹ̀yin obinrin, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀. Ẹ kọ́ àwọn ọmọ yín obinrin ní ẹkún sísun, kí ẹ sì kọ́ aládùúgbò yín ní orin arò. Nítorí ikú ti dé ojú fèrèsé wa, ó ti wọ ààfin wa. Ikú ń pa àwọn ọmọde nígboro, ati àwọn ọdọmọkunrin ní gbàgede.” Sọ wí pé, “Òkú eniyan yóo sùn lọ nílẹ̀ bí ìgbọ̀nsẹ̀ lórí pápá tí ó tẹ́jú, ati bíi ìtí ọkà lẹ́yìn àwọn tí wọn ń kórè ọkà, kò sì ní sí ẹni tí yóo kó wọn jọ. OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA ní, “Kí ọlọ́gbọ́n má fọ́nnu nítorí ọgbọ́n rẹ̀, kí alágbára má fọ́nnu nítorí agbára rẹ̀; kí ọlọ́rọ̀ má sì fọ́nnu nítorí ọrọ̀ rẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí ó bá fẹ́ fọ́nnu, ohun tí ó lè máa fi fọ́nnu ni pé òun ní òye ati pé òun mọ̀ pé, èmi OLUWA ni OLUWA tí ń ṣe ẹ̀tọ́, tí sì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òdodo hàn lórí ilẹ̀ ayé; nítorí pé àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ni mo ní inú dídùn sí.” Ó ní, “Ọjọ́ ń bọ̀, tí n óo fìyà jẹ àwọn tí a kọ nílà, ṣugbọn tí wọn ń ṣe bí aláìkọlà, àwọn ará Ijipti, àwọn ọmọ Juda, àwọn ará Edomu, ati àwọn ọmọ Amoni àwọn ará Moabu, ati gbogbo àwọn tí ń gbé inú aṣálẹ̀; tí wọn ń fá apá kan irun orí wọn; nítorí pé bí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi kò ṣe kọlà abẹ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ilẹ̀ Israẹli kò kọlà ọkàn.” Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí OLUWA ń ba yín sọ, ẹ̀yin ọmọ Israẹli: OLUWA ní, “Ẹ má kọ́ àṣà àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, ẹ má sì páyà nítorí àwọn àmì ojú ọ̀run, bí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tilẹ̀ ń páyà nítorí wọn, nítorí pé irọ́ ló wà nídìí àwọn àṣà wọn. Wọn á gé igi ninu igbó, agbẹ́gilére á fi àáké gbẹ́ ẹ. Wọn á fi fadaka ati wúrà ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́, wọn á sì fi ìṣó kàn án mọ́lẹ̀, kí ó má baà wó lulẹ̀. Ère wọn dàbí aṣọ́komásùn ninu oko ẹ̀gúsí, wọn kò lè sọ̀rọ̀, gbígbé ni wọ́n máa ń gbé wọn nítorí pé wọn kò lè dá rìn. Ẹ má bẹ̀rù wọn nítorí pé wọn kò lè ṣe ẹnikẹ́ni ní ibi kankan, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì lè ṣe rere.” OLUWA, kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ, o tóbi lọ́ba, agbára orúkọ rẹ sì pọ̀. Ta ni kò ní bẹ̀rù rẹ, ìwọ ọba àwọn orílẹ̀-èdè? Nítorí ẹ̀tọ́ rẹ ni; kò sì sí ẹni tí ó gbọ́n tó ọ láàrin àwọn ọlọ́gbọ́n tí wọ́n wà ní àwọn orílẹ̀-èdè, ati ni gbogbo ìjọba wọn. Aláìmọ̀kan ati òmùgọ̀ ni gbogbo wọn, ère kò lè kọ́ eniyan lọ́gbọ́n, nítorí igi lásán ni. Wọ́n kó fadaka pẹlẹbẹ wá láti ìlú Taṣiṣi, ati wúrà láti ìlú Ufasi. Iṣẹ́ ọwọ́ agbẹ́gilére ni wọ́n, ati ti àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà. Aṣọ wọn jẹ́ aláwọ̀ pupa ati ti elése àlùkò, iṣẹ́ ọwọ́ àwọn oníṣọ̀nà ni gbogbo wọn. Ṣugbọn OLUWA ni Ọlọrun tòótọ́, òun ni Ọlọrun alààyè, Ọba ayérayé. Tí inú rẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ síí ru ayé á mì tìtì, àwọn orílẹ̀-èdè kò lè farada ibinu rẹ̀. Wí fún wọn pé àwọn ọlọrun tí kì í ṣe àwọn ni wọ́n dá ọ̀run ati ayé yóo parun láyé ati lábẹ́ ọ̀run. Òun ni ó fi agbára rẹ̀ dá ayé, tí ó fi ọgbọ́n fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀, tí ó sì fi òye rẹ̀ ta ojú ọ̀run bí aṣọ. Bí ó bá fọhùn, omi á máa rọ́kẹ̀kẹ̀ lójú ọ̀run, ó mú kí ìkùukùu gbéra láti òpin ayé, òun ni ó dá mànàmáná fún òjò, tí ó sì mú afẹ́fẹ́ wá láti ilé ìṣúra rẹ̀. Òmùgọ̀ ni gbogbo eniyan jẹ́, wọn kò sì ní ìmọ̀; gbogbo àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà ni àwọn oriṣa wọn dójútì, nítorí pé irọ́ ló wà nídìí àwọn ère wọn; kò sí èémí ninu wọn. Asán ni wọ́n, ohun ìṣìnà sì ni wọ́n; ní àkókò ìjẹníyà wọn, wọn yóo parun ni. Ìpín Jakọbu kò rí bí àwọn wọnyi, nítorí òun ló dá ohun gbogbo, Israẹli sì ni ẹ̀yà tí ó yàn, gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀; OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀. Ẹ gbé ẹrù yín nílẹ̀, ẹ̀yin tí ọ̀tá dótì wọnyi! Nítorí OLUWA wí pé, “Mo ṣetán wàyí, tí n óo sọ àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ yìí nù bí òkò. N óo mú kí ìpọ́njú dé bá wọn, kí wọ́n lè mọ̀ pé nǹkan ṣe àwọn.” Mo gbé, nítorí mo fara gbọgbẹ́! Ọgbẹ́ náà sì pọ̀. Ṣugbọn mo sọ fún ara mi pé, “Ìyà gan-an ni èyí jẹ́ fún mi, mo sì gbọdọ̀ fara dà á.” Àgọ́ mi ti wó, gbogbo okùn rẹ̀ sì ti já. Àwọn ọmọ mi ti fi mí sílẹ̀, wọn kò sì sí mọ́. Kò sí ẹni tí yóo máa bá mi pa àgọ́ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí yóo máa bá mi ta aṣọ àgọ́ mi. Nítorí pé òmùgọ̀ ni àwọn olùṣọ́-aguntan, wọn kò sì ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ OLUWA, nítorí náà wọn kò ṣe àṣeyọrí, tí gbogbo agbo wọn sì fi túká. Ẹ gbọ́ àhesọ ọ̀rọ̀ kan! Ó ń tàn kálẹ̀! Ìdàrúdàpọ̀ ńlá ń bọ̀ láti ilẹ̀ àríwá, tí yóo sọ àwọn ìlú Juda di ahoro yóo sì di ibùgbé àwọn ajáko. OLUWA, mo mọ̀ pé ọ̀nà ẹ̀dá kò sí ní ọwọ́ ara rẹ̀. Kò sí ní ìkáwọ́ ẹni tí ń rìn láti tọ́ ìṣísẹ̀ ara rẹ̀. Tọ́ mi sọ́nà, OLUWA, ṣugbọn lọ́nà ẹ̀tọ́ ni kí o bá mi wí, kì í ṣe pẹlu ibinu rẹ, kí o má baà sọ mí di ẹni ilẹ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò mọ̀ ọ́, ni kí o bínú sí kí ó pọ̀, ati àwọn tí wọn kì í jọ́sìn ní orúkọ rẹ; nítorí pé wọ́n ti jẹ Jakọbu run, wọ́n jẹ ẹ́ ní àjẹrun patapata, wọ́n sì sọ ibùgbé rẹ̀ di ahoro. OLUWA bá èmi Jeremaya sọ̀rọ̀, ó ní, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ majẹmu yìí, kí o sì sọ ọ́ fún àwọn ọmọ Juda, ati àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu. Sọ fún wọn pé OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, ‘Ẹnikẹ́ni tí kò bá gba ọ̀rọ̀ majẹmu tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín, gbé! Majẹmu tí mo bá wọn dá ní ọjọ́ tí mo kó wọn kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, ilẹ̀ tí ó gbóná bí iná tí alágbẹ̀dẹ fi ń yọ́ irin.’ Mo sọ fún wọn nígbà náà, mo ní, ‘Ẹ máa fetí sí ohùn mi, kí ẹ sì máa ṣe gbogbo nǹkan tí mo pa láṣẹ fun yín. Òun ni ẹ óo fi jẹ́ eniyan mi, tí èmi náà óo sì fi jẹ́ Ọlọrun yín. Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, n óo mú ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́ fún àwọn baba ńlá yín ṣẹ, pé n óo fún wọn ní ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin,’ bí ó ti rí ní òní.” Mo bá dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, OLUWA.” OLUWA tún sọ fún mi pé, “Kéde gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ní àwọn ìlú Juda ati ní àwọn òpópó Jerusalẹmu, pé kí wọn fetí sí ọ̀rọ̀ majẹmu yìí, kí wọ́n sì ṣe bí ó ti wí. Mo kìlọ̀ fún àwọn baba ńlá yín ní ọjọ́ tí mo kó wọn kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, títí tí ó sì fi di òní, n kò yé kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n fetí sí ohùn èmi OLUWA. Sibẹsibẹ wọn kò gbọ́; wọn kò sì fetí sí ọ̀rọ̀ mi. Kàkà bẹ́ẹ̀, olukuluku ń ṣe ohun tí ó wà ní ọkàn burúkú rẹ̀. Nítorí náà ni mo ṣe mú kí gbogbo ọ̀rọ̀ majẹmu yìí ṣẹ mọ́ wọn lára, bí mo ti pa á láṣẹ fún wọn pé kí wọn ṣe, ṣugbọn tí wọn kò ṣe.” OLUWA tún wí fún mi pé, “Àwọn ọmọ Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu ń dìtẹ̀. Wọ́n ti pada sí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wọn, tí wọ́n kọ̀, tí wọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Wọ́n ti bá àwọn ọlọrun mìíràn lọ, wọ́n sì ń sìn wọ́n. Àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn ọmọ Juda ti da majẹmu tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá. Nítorí náà, OLUWA ní, òun óo mú kí ibi ó dé bá wọn, ibi tí wọn kò ní lè bọ́ ninu rẹ̀. Ó ní bí wọ́n tilẹ̀ ké pe òun, òun kò ní fetí sí tiwọn. Ó ní àwọn ìlú Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu yóo ké pe àwọn oriṣa tí wọn ń sun turari sí, ṣugbọn àwọn oriṣa kò ní lè gbà wọ́n lọ́jọ́ ìṣòro. Bí àwọn ìlú ti pọ̀ tó ní ilẹ̀ Juda bẹ́ẹ̀ ni àwọn oriṣa ibẹ̀ pọ̀ tó. Bákan náà, Jerusalẹmu, bí òpópó ṣe pọ̀ tó ní Jerusalẹmu, bẹ́ẹ̀ náà ni pẹpẹ tí wọ́n fi ń sun turari sí Baali, tí ó jẹ́ ohun ìtìjú, ṣe pọ̀ tó ninu rẹ̀. “Nítorí náà, má ṣe gbadura fún àwọn eniyan wọnyi. Má sọkún nítorí wọn, má sì bẹ̀bẹ̀ fún wọn, nítorí n kò ní gbọ́, nígbà tí wọn bá ké pè mí nígbà ìṣòro wọn. “Ẹ̀tọ́ wo ni olólùfẹ́ mi níláti wà ninu ilé mi lẹ́yìn tí ó ti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ inú rẹ̀? Ṣé ọpọlọpọ ẹ̀jẹ́ ati ẹran tí a fi rúbọ lè mú kí ibi rékọjá rẹ̀? Ṣé ó lè máa yọ̀ nígbà náà? Nígbà kan rí, OLUWA pè ọ́ ní igi olifi eléwé tútù, tí èso rẹ̀ dára; ṣugbọn pẹlu ìró ìjì ńlá, yóo dáná sun ún, gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ yóo sì jóná. OLUWA àwọn ọmọ ogun tí ó gbìn ọ́, ti ṣe ìdájọ́ ibi fún ọ, nítorí iṣẹ́ ibi tí ẹ ṣe, ẹ̀yin ilé Israẹli ati ilé Juda; ẹ mú mi bínú nítorí pé ẹ sun turari sí oriṣa Baali.” OLUWA fi iṣẹ́ ibi wọn hàn mí, ó sì yé mi. Ṣugbọn mo dàbí ọ̀dọ́ aguntan tí wọn ń fà lọ sọ́dọ̀ alápatà. N kò mọ̀ pé nítorí mi ni wọ́n ṣe ń gbèrò ibi, tí wọn ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á gé igi náà lulẹ̀ pẹlu èso rẹ̀, kí á gé e kúrò ní ilẹ̀ alààyè, kí á má sì ranti orúkọ rẹ̀ mọ́.” Ṣugbọn onídàájọ́ òdodo ni ọ́, OLUWA àwọn ọmọ ogun, ẹni tí ó ń dán ọkàn ati èrò eniyan wò, jẹ́ kí n rí i bí o óo ṣe máa gbẹ̀san lára wọn; nítorí pé ìwọ ni mo fi ọ̀rọ̀ mi lé lọ́wọ́. Nítorí náà, OLUWA sọ nípa àwọn ará Anatoti, tí wọn ń wá ẹ̀mí Jeremaya, tí wọn sì ń sọ fún un pé, “O kò gbọdọ̀ sọ àsọtẹ́lẹ̀ mọ́ ní orúkọ OLUWA. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa ni a óo pa ọ́.” Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun ní òun óo jẹ wọ́n níyà; àwọn ọdọmọkunrin wọn yóo kú lójú ogun, ìyàn ni yóo sì pa àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin wọn. Kò ní sí ẹni tí yóo ṣẹ́kù nítorí pé òun óo mú kí ibi dé bá àwọn ará Anatoti, nígbà tí àkókò bá tó tí òun óo jẹ wọ́n níyà. Olódodo ni ọ́, OLUWA, nígbà tí mo bá ń fẹjọ́ sùn ọ́; sibẹ n óo ro ẹjọ́ mi níwájú rẹ. Kí ló dé tí nǹkan ń dára fún àwọn eniyan burúkú? O gbìn wọ́n, wọ́n ta gbòǹgbò; wọ́n dàgbà, wọ́n so èso; orúkọ rẹ kò jìnnà sẹ́nu wọn, ṣugbọn ọkàn wọn jìnnà sí ọ. Ṣugbọn ìwọ OLUWA mọ̀ mí, O rí mi, o sì ti yẹ ọkàn mi wò o mọ èrò mi sí ọ. Fà wọ́n jáde bí aguntan tí wọn ń mú lọ pa, yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ọjọ́ ìparun. Yóo ti pẹ́ tó, tí ilẹ̀ náà yóo máa ṣọ̀fọ̀, tí koríko oko yóo rọ? Nítorí iṣẹ́ burúkú àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀, àwọn ẹranko ati àwọn ẹyẹ ṣègbé, nítorí àwọn eniyan ń wí pé, “Kò ní rí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí wa.” OLUWA ní, “Bí o bá àwọn tí ń fi ẹsẹ̀ sáré sáré, tí ó bá rẹ̀ ọ́, báwo ni o ṣe lè bá ẹṣin sáré? Bí o bá sì ń ṣubú ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú, báwo ni o óo ti ṣe nígbà tí o bá dé aṣálẹ̀ Jọdani? Nítorí pé àwọn arakunrin rẹ pàápàá ati àwọn ará ilé baba rẹ ti hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí ọ; àwọn gan-an ni wọ́n ń ṣe èké rẹ: Má gbẹ́kẹ̀lé wọn, bí wọ́n bá tilẹ̀ ń sọ̀rọ̀ rere sí ọ.” OLUWA wí pé, “Mo ti kọ ilé mi sílẹ̀; mo ti kọ ogún tí a pín fún mi sílẹ̀. Mo ti fa ẹni tí ọkàn mi ń fẹ́ lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́. Ogún mi ti dàbí kinniun inú igbó sí mi, ó ti sọ̀rọ̀ burúkú sí mi; nítorí náà mo kórìíra rẹ̀. Ṣé ogún mi ti dàbí ẹyẹ igún aláwọ̀ adíkálà ni? Ṣé àwọn ẹyẹ igún ṣùrù bò ó ni? Ẹ lọ pe gbogbo àwọn ẹranko igbó jọ, ẹ kó wọn wá jẹun. Ọpọlọpọ àwọn darandaran ni wọ́n ti ba ọgbà àjàrà mi jẹ́, wọ́n ti tẹ oko mi mọ́lẹ̀, wọ́n sọ oko mi dáradára di aṣálẹ̀. Wọ́n sọ ọ́ di ahoro, ilẹ̀ pàápàá ń ráhùn sí mi. Wọ́n ti sọ gbogbo ilẹ̀ náà di ahoro, ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò bìkítà fún un. Àwọn apanirun ti dé sí gbogbo àwọn òkè inú pápá, nítorí pé idà Ọlọrun ni ó ń run eniyan, jákèjádò ilẹ̀ náà; ẹnikẹ́ni kò ní alaafia, Ọkà baali ni wọ́n gbìn, ṣugbọn ẹ̀gún ni wọ́n kórè. Wọ́n ṣe làálàá, ṣugbọn wọn kò jèrè kankan. Ojú yóo tì wọ́n nígbà ìkórè, nítorí ibinu gbígbóná OLUWA.” Ohun tí OLUWA sọ nípa gbogbo àwọn aládùúgbò burúkú mi nìyí, àwọn tí wọn ń jí bù lára ilẹ̀ tí mo fún Israẹli, àwọn eniyan mi. Ó ní, “N óo kó wọn kúrò lórí ilẹ̀ wọn; n óo sì kó àwọn ọmọ Juda kúrò láàrin wọn. Lẹ́yìn tí mo bá kó wọn kúrò tán, n óo pada ṣàánú wọn, n óo dá olukuluku pada sí ilẹ̀ ìní rẹ̀. Nígbà tí ó bá yá, bí wọ́n bá fi tọkàntọkàn kọ́ àṣà àwọn eniyan mi, tí wọ́n sì ń fi orúkọ mi búra, tí wọn ń wí pé, ‘Bí OLUWA Ọlọrun ti wà láàyè’, bí àwọn náà ṣe kọ́ àwọn eniyan mi láti máa fi orúkọ Baali búra, n óo fi ìdí wọn múlẹ̀ láàrin àwọn eniyan mi. Ṣugbọn bí orílẹ̀-èdè kan bá ṣe àìgbọràn, n óo yọ ọ́ kúrò patapata, n óo sì pa á run. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA sọ fún mi pé, “Lọ ra aṣọ funfun kan, kí o lọ́ ọ mọ́ ìdí, má sì tì í bọ omi rárá.” Mo bá ra aṣọ funfun náà, bí OLUWA ti wí, mo lọ́ ọ mọ́ ìdí. OLUWA tún sọ fún mi lẹẹkeji pé, “Dìde, mú aṣọ funfun tí o rà, tí o lọ́ mọ́ ìdí, lọ sí odò Yufurate, kí o lọ fi pamọ́ sí ihò àpáta níbẹ̀.” Mo bá lọ fi pamọ́ sí ẹ̀bá odò Yufurate bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún mi. Lẹ́yìn ọpọlọpọ ọjọ́, OLUWA sọ fún mi pé, “Dìde, lọ sí odò Yufurate kí o mú aṣọ tí mo ní kí o fi pamọ́ sibẹ wá.” Mo bá lọ sí ẹ̀bá odò Yufurate; mo gbẹ́ ilẹ̀, mo yọ aṣọ funfun náà jáde kúrò ní ibi tí mo bò ó mọ́. Ó ti bàjẹ́; kò sì wúlò fún ohunkohun mọ́. OLUWA sọ fún mi pé, “Bẹ́ẹ̀ gan-an ni n óo ṣe sọ ògo Juda ati ti Jerusalẹmu di ìbàjẹ́. Àwọn ẹni ibi wọnyi, tí wọ́n kọ̀, tí wọn kò gbọ́ tèmi, tí wọn ń fi oríkunkun tẹ̀lé ìfẹ́ ọkàn wọn, tí wọ́n sì ti sá tọ àwọn oriṣa lọ, tí wọn ń sìn wọ́n, tí wọn sì ń bọ wọ́n. Wọn yóo dàbí aṣọ yìí tí kò wúlò fún ohunkohun. Bí aṣọ ìlọ́dìí tií lẹ̀ mọ́ ọkunrin lára, bẹ́ẹ̀ ni mo mú kí gbogbo ilé Israẹli ati gbogbo ilé Juda súnmọ́ mi, kí wọ́n lè jẹ́ eniyan mi, ati orúkọ mi, ìyìn mi, ati ògo mi. Ṣugbọn wọ́n kọ̀, wọn kò gbọ́.” OLUWA ní, “Sọ fún wọn pé, èmi OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, ‘Gbogbo ìkòkò ni a óo rọ ọtí waini kún.’ Wọn yóo dá ọ lóhùn pé, ‘Ṣé a kò mọ̀ pé gbogbo ìkòkò ni a óo rọ ọtí waini kún ni?’ Ìwọ wá wí fún wọn pé, èmi OLUWA ní n óo rọ àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ yìí ní ọtí àrọyó, ati àwọn ọba tí wọn jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, ati àwọn alufaa, àwọn wolii ati gbogbo àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu. N óo máa sọ wọ́n lu ara wọn. Baba ati ọmọ yóo máa kọlu ara wọn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N kò ní ṣàánú wọn, n kò ní dá ẹnikẹ́ni sí, n kò sì ní yọ́nú sí wọn débi pé kí n má fẹ́ pa wọ́n run.” Ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ gbọ́, ẹ má gbéraga nítorí pé OLUWA ló sọ̀rọ̀. Ẹ fi ògo fún OLUWA Ọlọrun yín kí ó tó mú òkùnkùn ṣú. Kí ẹ tó bẹ̀rẹ̀ sí fẹsẹ̀ kọ lórí òkè, níbi tí kò sí ìmọ́lẹ̀. Nígbà tí ẹ bá ń wá ìmọ́lẹ̀, yóo sọ ọ́ di ìṣúdudu, yóo sọ ọ́ di òkùnkùn biribiri. Ṣugbọn bí ẹ kò bá ní gbọ́, ọkàn mi yóo sọkún níkọ̀kọ̀ nítorí ìgbéraga yín. N óo sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, omi yóo sì máa dà lójú mi, nítorí a ti kó agbo OLUWA ní ìgbèkùn. Wí fún ọba ati ìyá ọba pé, “Ẹ sọ̀kalẹ̀ lórí ìtẹ́ yín, nítorí adé yín tí ó lẹ́wà ti ṣí bọ́ sílẹ̀ lórí yín.” Wọ́n ti sé ìlẹ̀kùn odi àwọn ìlú ilẹ̀ Nẹgẹbu kò sì sí ẹni tí yóo ṣí wọn. A ti kó gbogbo Juda lọ sí ìgbèkùn, gbogbo wọn pátá ni a ti kó lọ. Ẹ gbé ojú sókè, kí ẹ wo àwọn tí ń bọ̀ láti ìhà àríwá. Àwọn agbo ẹran tí a fun yín dà, àwọn ẹran ọ̀sìn yín tí ó lẹ́wà àwọn dà? Kí ni ẹ óo máa wí nígbà tí OLUWA bá mú àwọn tí ẹ fi ṣe ọ̀rẹ́, tí ó fi wọ́n jọba le yín lórí? Ǹjẹ́ ìnira kò ní ba yín, bí ìrora obinrin tí ń rọbí? Bí ẹ bá wí lọ́kàn yín pé, “Kí ló dé tí irú èyí fi dé bá wa?” Ẹ̀ṣẹ̀ yín ni ó pọ̀, ni a fi ká aṣọ ní ìdí yín, tí a sì jẹ yín níyà. Ṣé ó ṣeéṣe kí ará Kuṣi yí àwọ̀ ara rẹ̀ pada? Àbí kí àmọ̀tẹ́kùn fọ tóótòòtóó ara rẹ̀ dànù? Bí ó bá ṣeéṣe, á jẹ́ wí pé ẹ̀yin náà lè hùwà rere; ẹ̀yin tí ibi ṣíṣe ti mọ́ lára. N óo fọn yín ká bí ìyàngbò tí afẹ́fẹ́ láti inú aṣálẹ̀ ń fẹ́ kiri. Èyí ni ìpín yín, ìpín tí mo ti yàn fun yín, nítorí pé ẹ ti gbàgbé èmi OLUWA, ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé ọlọrun èké. Èmi gan-an ni n óo ká aṣọ lára yín, n óo sì fi bò yín lójú, kí ayé lè rí ìhòòhò yín. Mo ti rí ìwà ìbàjẹ́ yín, gbogbo ìwà àgbèrè yín, bí ẹ tí ń yan ká bí akọ ẹṣin, ati ìwà ìṣekúṣe yín ní orí àwọn òkè ninu pápá. Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ẹ gbé! Yóo ti pẹ́ tó kí á tó wẹ̀ yín mọ́? Ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ fún Jeremaya nípa ọ̀gbẹlẹ̀ nìyí: “Juda ń ṣọ̀fọ̀, àwọn ẹnubodè ìlú rẹ̀ wà ninu ìnira. Àwọn eniyan inú rẹ̀ ń sọkún ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀, igbe àwọn ará Jerusalẹmu sì ta sókè. Àwọn ọlọ́lá ní ìlú rán àwọn iranṣẹ wọn lọ pọn omi, àwọn iranṣẹ dé odò, wọn kò rí omi. Wọ́n gbé ìkòkò omi wọn pada lófìfo, ojú tì wọ́n, ìdààmú dé bá wọn, wọ́n káwọ́ lérí. Nítorí ilẹ̀ tí ó gbẹ, nítorí òjò tí kò rọ̀ ní ilẹ̀ náà, ojú ti àwọn àgbẹ̀, wọ́n káwọ́ lérí. Àgbọ̀nrín inú igbó pàápàá já ọmọ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sílẹ̀, nítorí kò sí koríko. Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó dúró lórí òkè, wọ́n ń mí hẹlẹhẹlẹ bí ajáko. Ojú wọn rẹ̀wẹ̀sì, nítorí kò sí koríko. Àwọn eniyan mi ké pè mí wí pé, ‘Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ wa ń jẹ́rìí lòdì sí wa, sibẹsibẹ, nítorí orúkọ rẹ, gbà wá. Ọpọlọpọ ìgbà ni a ti pada lẹ́yìn rẹ, a ti ṣẹ̀ ọ́. Ìwọ ìrètí Israẹli, olùgbàlà rẹ̀ ní ìgbà ìṣòro. Kí ló dé tí o óo fi dàbí àlejò ní ilẹ̀ náà? Àní, bí èrò ọ̀nà, tí ó yà láti sùn mọ́jú? Kí ló dé tí o fi dàbí ẹni tí ìdààmú bá; bí alágbára tí kò lè gbani là? Bẹ́ẹ̀ ni o wà láàrin wa, OLUWA, a sì ń fi orúkọ rẹ pè wá, má fi wá sílẹ̀.’ ” OLUWA sọ nípa àwọn eniyan náà pé, “Ó wù wọ́n láti máa ṣáko kiri, wọn kò ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ wọn; nítorí náà wọn kì í ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ OLUWA, nisinsinyii OLUWA yóo ranti àìdára wọn, yóo sì jẹ wọ́n níyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” OLUWA sọ fún mi pé, “Má gbadura pé kí àwọn eniyan wọnyi wà ní alaafia. Wọn ìbáà gbààwẹ̀, n kò ní gbọ́ igbe wọn. Wọn ìbáà rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ, n kò ní tẹ́wọ́ gbà wọ́n. Idà, ati ebi, ati àjàkálẹ̀ àrùn, ni n óo fi pa wọ́n run.” Mo bá dáhùn pé, “Háà! OLUWA Ọlọrun, wò ó! Àwọn wolii ń sọ fún wọn pé, wọn kò ní fojú kan ogun, tabi ìyàn, ati pé, alaafia tòótọ́ ni o óo fún wọn ní ibí yìí.” OLUWA bá sọ fún mi pé, “Àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ ni àwọn wolii ń sọ ní orúkọ mi, n kò rán wọn níṣẹ́, n kò fún wọn láṣẹ, n kò tilẹ̀ bá wọn sọ̀rọ̀. Ìran èké ni wọ́n ń rí; iṣẹ́ asán ni wọ́n ń wò. Ohun tí ó wà lọ́kàn wọn ni wọ́n ń sọ. Nítorí náà, ohun tí èmi OLUWA sọ ni pé, àwọn wolii tí n kò rán níṣẹ́, tí wọn ń jíṣẹ́ orúkọ mi, tí wọn ní èmi sọ pé ogun ati ìyàn kò ní wọ ilẹ̀ yìí, ogun ati ìyàn ni yóo pa àwọn gan-an run. Wọn óo gbé àwọn eniyan tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún sọ síta ní òkú ní ìgboro Jerusalẹmu, nígbà tí ìyàn ati ogun bá pa wọ́n tán. Kò ní sí ẹni tí yóo sin òkú wọn, ati ti àwọn iyawo wọn, ati ti àwọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin. N óo da ibi tí wọ́n ṣe lé wọn lórí.” OLUWA wí fun mi pé, “Sọ fún wọn pé, ‘Kí omijé máa ṣàn lójú mi tọ̀sán-tòru, kí ó má dáwọ́ dúró, nítorí ọgbẹ́ ńlá tí a fi tagbára tagbára ṣá eniyan mi. Bí mo bá jáde lọ sí ìgbèríko, àwọn tí wọ́n fi idà pa ni wọ́n kún bẹ̀! Bí mo bá sì wọ ààrin ìlú, àwọn tí ìyàn di àìsàn sí lára ni wọ́n kún bẹ̀. Nítorí àwọn wolii ati àwọn alufaa ń lọ káàkiri gbogbo ilẹ̀ náà, wọn kò sì mọ ohun tí wọn ń ṣe.’ ” OLUWA, ṣé o ti kọ Juda sílẹ̀ patapata ni? Àbí Sioni ti di ohun ìríra lọ́kàn rẹ? Kí ló dé tí o fi lù wá, tóbẹ́ẹ̀ tí ọ̀rọ̀ tiwa kọjá ìwòsàn? À ń retí alaafia, ṣugbọn ire kankan kò dé. À ń retí àkókò ìwòsàn, ṣugbọn ìpayà ni a rí. OLUWA, a mọ ìwà burúkú wa, ati ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wa, nítorí a ti ṣẹ̀ ọ́. Má ta wá nù nítorí orúkọ rẹ, má sì fi àbùkù kan ìtẹ́ rẹ tí ó lógo. Ranti majẹmu tí o bá wa dá, ranti, má sì ṣe dà á. Ninu gbogbo àwọn ọlọrun èké tí àwọn orílẹ̀-èdè ń sìn, ǹjẹ́ ọ̀kan wà tí ó lè mú kí òjò rọ̀? Àbí ojú ọ̀run ní ń fúnrarẹ̀ rọ ọ̀wààrà òjò? OLUWA Ọlọrun wa, ṣebí ìwọ ni? Ìwọ ni a gbẹ́kẹ̀lé, nítorí ìwọ ni o ṣe gbogbo nǹkan wọnyi. OLUWA bá tún sọ fún mi pé, “Mose ati Samuẹli ìbáà wá dúró níwájú mi, ọkàn mi kò lè yọ́ sí àwọn eniyan wọnyi. Lé wọn kúrò níwájú mi, kí wọ́n máa lọ! Bí wọ́n bá bi ọ́ pé níbo ni kí àwọn ó lọ, sọ fún wọn pé èmi OLUWA ní, ‘Àwọn tí wọn yóo kú ikú àjàkálẹ̀ àrùn, kì àjàkálẹ̀ àrùn pa wọ́n; àwọn tí wọn yóo kú ikú ogun, kí ogun pa wọ́n. Àwọn tí wọn yóo kú ikú ìyàn, kí ìyàn pa wọ́n; àwọn tí wọn yóo lọ sí ìgbèkùn, kí ogun kó wọn lọ.’ Oríṣìí ìparun mẹrin ni n óo jẹ́ kí ó dé bá wọn: idà óo pa wọ́n, ajá óo fà wọ́n ya, àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko óo jẹ wọ́n ní àjẹrun. N óo sọ wọ́n di ohun tí ó bani lẹ́rù fún gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé, nítorí ohun tí Manase, ọmọ Hesekaya, ọba Juda, ṣe ní Jerusalẹmu.” OLUWA ní, “Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ta ni yóo ṣàánú yín? Ta ni yóo dárò yín? Ta ni yóo ya ọ̀dọ̀ yín, láti bèèrè alaafia yín? Ẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀, ẹ sì ń pada lẹ́yìn mi; èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Nítorí náà ni mo ṣe na ọwọ́ ibinu mi si yín, tí mo sì pa yín run. Mo ti mú sùúrù, ó ti sú mi. Mo ti fẹ́ wọn bí ẹni fẹ́ ọkà ní ibi ìpakà, ní ẹnubodè ilẹ̀ náà. Mo ti kó ọ̀fọ̀ bá wọn; mo ti pa àwọn eniyan mi run, nítorí wọn kò yipada kúrò ní ọ̀nà wọn. Mo ti mú kí opó pọ̀ láàrin wọn ju iyanrìn inú òkun lọ. Mo mú kí apanirun gbógun ti àwọn ìyá àwọn ọdọmọkunrin ní ọ̀sán gangan. Mo mú kí ìbẹ̀rù ati ìwárìrì já lù wọ́n láìròtẹ́lẹ̀. Ẹni tí ó bí ọmọ meje ṣe àárẹ̀, ó sì dákú, oòrùn rẹ̀ wọ̀ lọ́sàn-án gangan. Ìtìjú ati àbùkù bá a. N óo jẹ́ kí ọ̀tá fi idà pa àwọn tí wọ́n kù ninu wọn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” Mo gbé! Ìyá mi, kí ló dé tí o bí mi, èmi tí mo di oníjà ati alárìíyànjiyàn láàrin gbogbo ìlú! N kò yá ẹnikẹ́ni lówó, bẹ́ẹ̀ n kò yáwó lọ́wọ́ ẹnìkan, sibẹsibẹ gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣépè lé mi. Kí èpè wọn mọ́ mi, OLUWA, bí n kò bá sọ ọ̀rọ̀ wọn ní rere níwájú rẹ, bí n kò bá gbadura fún àwọn ọ̀tá mi ní àkókò ìyọnu ati ìdààmú wọn. Ǹjẹ́ ẹnìkan lè ṣẹ́ irin, pàápàá, irin ilẹ̀ àríwá tí wọn fi idẹ lú? OLUWA bá dáhùn pé, “Nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, n óo fi ọrọ̀ ati ohun ìṣúra rẹ fún àwọn tí ń kó ìkógun ní gbogbo agbègbè rẹ, láìgba owó lọ́wọ́ wọn. N óo mú kí o sin àwọn ọ̀tá rẹ ní ilẹ̀ tí o kò dé rí. Mo ti fi ibinu dá iná kan, ó ti ràn, yóo máa jó ọ, kò sì ní kú laelae.” Mo bá dáhùn pé, “OLUWA, ṣebí ìwọ náà mọ̀? Ranti mi, kí o sì ràn mí lọ́wọ́. Gbẹ̀san mi lára àwọn tí wọn ń ṣe inúnibíni sí mi. Má mú mi kúrò nítorí ojú àánú rẹ. Ranti pé nítorí rẹ ni wọ́n ṣé ń fi mí ṣẹ̀sín. Nígbà tí mo rí ọ̀rọ̀ rẹ, mo fi ṣe oúnjẹ jẹ. Nǹkan ayọ̀ ni ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fún mi, ó sì jẹ́ ìdùnnú ọkàn mi. Nítorí orúkọ rẹ ni a fi ń pè mí, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun. N kò jókòó láàrin àwọn alárìíyá, bẹ́ẹ̀ ni n kò yọ̀. Mo dá jókòó nítorí àṣẹ rẹ, nítorí o ti fi ìrúnú kún ọkàn mi. Kí ló dé tí ìrora mi kò dáwọ́ dúró, tí ọgbẹ́ mi jinlẹ̀, tí ó kọ̀, tí kò san? Ṣé o fẹ́ dá mi lọ́kàn le lásán ni; bí ẹlẹ́tàn odò tíí gbẹ nígbà ẹ̀ẹ̀rùn?” Nítorí náà OLUWA ní, “Bí o bá yipada, n óo mú ọ pada sípò rẹ, o óo sì tún máa ṣe iranṣẹ mi. Bí o bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀ gidi, tí o dákẹ́ ìsọkúsọ, o óo tún pada di òjíṣẹ́ mi. Àwọn ni yóo pada tọ̀ ọ́ wá, o kò ní tọ̀ wọ́n lọ. N óo sọ ọ́ di odi alágbára tí a fi idẹ mọ, lọ́dọ̀ àwọn eniyan wọnyi. Wọn yóo gbógun tì ọ́, ṣugbọn wọn kò ní ṣẹgun rẹ, nítorí pé mo wà pẹlu rẹ láti gbà ọ́, ati láti yọ ọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú, n óo sì rà ọ́ pada lọ́wọ́ àwọn ìkà, aláìláàánú eniyan.” OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “O kò gbọdọ̀ fẹ́ iyawo tabi kí o bímọ ní ibí yìí. Nítorí ohun tí OLUWA sọ nípa àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin tí a bí ní ibí yìí, ati nípa ìyá tí ó bí wọn, ati baba tí a bí wọn fún ni pé, àìsàn burúkú ni yóo pa wọ́n. Ẹnìkan kò ní ṣọ̀fọ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní sin wọ́n; bí ìgbọ̀nsẹ̀ ni wọn yóo rí lórí ilẹ̀. Ogun ati ìyàn ni yóo pa wọ́n run, òkú wọn yóo sì di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko. “Má wọ ilé tí wọ́n ti ń ṣọ̀fọ̀, má lọ máa kọrin arò, tabi kí o bá wọn kẹ́dùn, nítorí mo ti mú alaafia mi ati ìfẹ́ mi ati àánú mi kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan wọnyi. Àtàwọn eniyan pataki pataki, ati mẹ̀kúnnù, ni yóo kú ní ilẹ̀ yìí, wọn kò ní rí ẹni sin òkú wọn, kò ní sí ẹni tí yóo sọkún wọn; ẹnìkan kò ní fi abẹ ya ara, tabi kí ẹnìkan fá orí nítorí wọn. Kò ní sí ẹni tí yóo fún ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ní oúnjẹ láti tù ú ninu, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kò sì ní bu omi fún ẹnìkan mu, nítorí ikú baba tabi ìyá rẹ̀. “O kò gbọdọ̀ lọ sí ilé tí wọ́n ti ń se àsè, má bá wọn jókòó láti jẹ tabi láti mu. Nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní: ‘Wò ó! N óo fi òpin sí ẹ̀rín ati ìró ayọ̀ ní ibí yìí, n óo sì fi òpin sí ohùn iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé ati ti ọkọ iyawo. Yóo ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ níṣojú yín, ní ìgbà ayé yín.’ “Bí o bá sọ ọ̀rọ̀ yìí fún àwọn eniyan náà tán, bí wọn bá bi ọ́ pé, ‘Kí ló dé tí OLUWA fi sọ gbogbo ọ̀rọ̀ burúkú yìí nípa wa? Kí ni a ṣe? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni a ṣẹ OLUWA Ọlọrun wa?’ Kí o dá wọn lóhùn pé, nítorí pé àwọn baba wọn ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n ń tẹ̀lé àwọn ọlọrun mìíràn, wọ́n ń sìn wọ́n, wọ́n sì ń bọ wọ́n. Wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọn kò sì pa òfin mi mọ́. Ẹ̀yin gan-an ti ṣe ohun tí ó burú ju ti àwọn baba yín lọ, ẹ wò bí olukuluku yín tí ń tẹ̀lé agídí ọkàn rẹ̀, tí ẹ kọ̀, tí ẹ kò sì gbọ́ tèmi. Nítorí náà, n óo gba yín dànù kúrò ní ilẹ̀ yìí; n óo fọn yín dànù bí òkò, sí ilẹ̀ tí ẹ̀yin ati àwọn baba yín kò mọ̀ rí. Níbẹ̀ ni ẹ óo ti máa sin oriṣa, tí ẹ óo máa bọ wọ́n tọ̀sán-tòru, nítorí pé n kò ní ṣàánú yín.” Nítorí náà, OLUWA ní, “Àkókò ń bọ̀, tí wọn kò ní máa búra mọ́ pé, ‘Bí OLUWA, tí ó kó àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti tí ń bẹ,’ ṣugbọn wọn yóo máa búra pé, ‘Bí OLUWA tí ń bẹ, ẹni tí ó kó àwọn ọmọ Israẹli jáde láti ilẹ̀ àríwá ati láti gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó lé wọn lọ.’ N óo mú wọn pada sórí ilẹ̀ wọn, ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba wọn.” Ó ní, “Wò ó, n óo ranṣẹ pe ọpọlọpọ apẹja, wọn yóo sì wá kó àwọn eniyan wọnyi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà, n óo ranṣẹ sí ọpọlọpọ ọdẹ, wọn yóo sì wá dọdẹ wọn ní orí gbogbo òkè gíga ati àwọn òkè kéékèèké, ati ninu pàlàpálá àpáta. Nítorí pé mò ń wo gbogbo ohun tí wọn ń ṣe, kò sí èyí tí n kò rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀ṣẹ̀ wọn kò sápamọ́ fún mi. N óo gbẹ̀san àìdára wọn, ati ẹ̀ṣẹ̀ wọn ní ìlọ́po meji, nítorí wọ́n ti fi ohun ìríra wọn sọ ilẹ̀ mi di eléèérí. Wọ́n sì ti kó oriṣa ìríra wọn kún ilẹ̀ mi.” OLUWA, ìwọ ni agbára mi, ati ibi ààbò mi, ìwọ ni ibi ìsápamọ́sí mi, ní ìgbà ìpọ́njú. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo wá sọ́dọ̀ rẹ, láti gbogbo òpin ayé, wọn yóo máa wí pé: “Irọ́ patapata ni àwọn baba wa jogún, ère lásánlàsàn tí kò ní èrè kankan. Ṣé eniyan lè fi ọwọ́ ara rẹ̀ ṣẹ̀dá ọlọrun? Irú ọlọrun bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ọlọrun rárá.” OLUWA ní, “Nítorí náà, wò ó, n óo jẹ́ kí wọn mọ̀; àní sẹ́, n óo jẹ́ kí wọ́n mọ agbára ati ipá mi; wọn yóo sì mọ̀ pé orúkọ mi ni OLUWA.” OLUWA ní, “Gègé irin ni a fi kọ ẹ̀ṣẹ̀ Juda sílẹ̀ gègé òkúta dayamọndi ni a sì fi kọ ọ́ sí ọkàn yín, ati sí ara ìwo ara pẹpẹ wọn, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọmọ yín bá ń ranti àwọn pẹpẹ yín, ati àwọn oriṣa Aṣera yín, tí ẹ rì mọ́ ẹ̀gbẹ́ gbogbo igi tútù, ati lórí àwọn òkè gíga; ati lórí àwọn òkè ninu pápá. N óo sọ gbogbo ọrọ̀ yín ati gbogbo ohun ìṣúra yín di ìkógun fún àwọn ọ̀tá yín; n óo fi gbẹ̀san ẹ̀ṣẹ̀ yín ní gbogbo ilẹ̀ yín. Ìwà yín yóo mú kí ilẹ̀ tí mo fun yín bọ́ lọ́wọ́ yín; n óo sí sọ yín di ẹrú àwọn ọ̀tá yín ní ilẹ̀ tí ẹ kò mọ̀rí. Ẹ ti mú kí ibinu mi máa jó bí iná, kò sì ní kú títí lae.” OLUWA ní, “Ègún ni fún ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé eniyan, tí ó fi ẹlẹ́ran ara ṣe agbára rẹ̀; tí ọkàn rẹ̀ yipada kúrò lọ́dọ̀ èmi OLUWA. Ó dàbí igbó ṣúúrú ninu aṣálẹ̀, nǹkan rere kan kò lè ṣẹlẹ̀ sí i. Ninu ilẹ̀ gbígbẹ, ninu aṣálẹ̀ ni ó wà, ninu ilẹ̀ iyọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè gbé. “Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, tí ó fi OLUWA ṣe àgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀. Yóo dàbí igi tí a gbìn sí ipa odò, tí ó ta gbòǹgbò kan ẹ̀bá odò. Ẹ̀rù kò ní bà á nígbà tí ẹ̀ẹ̀rùn bá dé, nítorí pé ewé rẹ̀ yóo máa tutù minimini. Kò ní páyà lákòókò ọ̀gbẹlẹ̀, nígbà gbogbo ni yóo sì máa so. “Ọkàn eniyan kún fún ẹ̀tàn ju ohun gbogbo lọ, ìwà ìbàjẹ́ sì kún inú rẹ̀; ta ni ó lè mọ èrò ọkàn eniyan? Èmi OLUWA ni èmi máa ń wádìí èrò eniyan, tí èmi sì máa ń yẹ ọkàn eniyan wò, láti san án fún olukuluku gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, ati gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” Bí àparò tíí pa ẹyin ẹlẹ́yin bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó fi èrú kó ọrọ̀ jọ. Ọrọ̀ yóo lọ mọ́ ọn lọ́wọ́ lọ́sàn-án gangan, nígbẹ̀yìn yóo di òmùgọ̀. Ìtẹ́ ògo tí a tẹ́ sí ibi gíga láti ìbẹ̀rẹ̀ ni ibi mímọ́ wa. OLUWA, ìwọ ni Israẹli gbójú lé, ojú yóo ti gbogbo àwọn tí wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀. A óo kọ orúkọ àwọn tí wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀ sórí ilẹ̀, yóo sì parẹ́, nítorí pé wọ́n ti kọ OLUWA, orísun omi ìyè, sílẹ̀. Wò mí sàn, OLUWA, ara mi yóo sì dá, gbà mí, n óo sì bọ́ ninu ewu. Nítorí pé ìwọ ni mò ń yìn. Wò ó! Wọ́n ń bi mí pé, “Níbo ni gbogbo ìhàlẹ̀ OLUWA já sí? Jẹ́ kí ó ṣẹ, kí á rí i!” N kò bẹ̀bẹ̀ pé kí o rán ibi sí wọn, bẹ́ẹ̀ ni n kò fẹ́ ọjọ́ ibi fún wọn. OLUWA, o mọ̀ bẹ́ẹ̀. Ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu mi jáde kò tún lè ṣàjèjì sí ọ. Má di ohun ẹ̀rù fún mi, nítorí ìwọ ni ibi ààbò mi ní ọjọ́ ibi. Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn tí wọn ń ṣe inúnibíni mi, ṣugbọn kí ojú má tì mí. Jẹ́ kí ìpayà bá wọn, ṣugbọn má jẹ́ kí èmi páyà. Mú ọjọ́ ibi dé bá wọn; pa wọ́n run ní àpatúnpa. OLUWA sọ fún mi pé, “Lọ dúró ní ẹnubodè Bẹnjamini níbí, tí àwọn ọba Juda máa ń gbà wọlé, tí wọn sìí gbà jáde; ati ní gbogbo ẹnubodè Jerusalẹmu, kí o wí pé, ‘Ẹ gbọ́ bí OLUWA ti wí, ẹ̀yin ọba Juda, ati gbogbo ẹ̀yin ará Juda ati gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gba ẹnu ọ̀nà wọnyi wọlé. OLUWA ní kí ẹ ṣọ́ra fún ẹ̀mí yín, ẹ má máa ru ẹrù ní ọjọ́ ìsinmi, ẹ má gbé ẹrù wọ ẹnubodè Jerusalẹmu ní ọjọ́ ìsinmi mọ́. Ẹ kò gbọdọ̀ ru ẹrù jáde ní ilé yín ní ọjọ́ ìsinmi. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan, ẹ níláti ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́, bí mo ti pa á láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín. Sibẹ àwọn baba yín kò gbọ́; wọn kò sì fetí sílẹ̀, wọ́n ṣe oríkunkun, kí wọn má baà gbọ́, kí wọn má baà gba ìtọ́ni. Ṣugbọn bí ẹ̀yin bá fetí sí ọ̀rọ̀ mi, tí ẹ kò gbé ẹrù wọ inú ìlú yìí lọ́jọ́ ìsinmi, tí ẹ ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́ láìṣe iṣẹ́ kankan lọ́jọ́ náà, àwọn ọba tí yóo máa gúnwà lórí ìtẹ́ Dafidi, yóo máa gba ẹnubodè ìlú yìí wọlé. Àwọn ati àwọn ìjòyè wọn, ati àwọn ará Juda ati ará ìlú Jerusalẹmu yóo máa gun ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun wọlé. Àwọn eniyan yóo sì máa gbé ìlú yìí títí ayé. Àwọn eniyan yóo máa wá láti gbogbo ìlú Juda ati àwọn agbègbè Jerusalẹmu, láti ilẹ̀ Bẹnjamini ati pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣefela, láti àwọn agbègbè olókè ati ilẹ̀ Nẹgẹbu, wọn yóo máa mú ẹbọ sísun ati ẹbọ ọrẹ wá, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati turari; wọn yóo máa mú ẹbọ ọpẹ́ wá sí ilé OLUWA. Ṣugbọn bí ẹ kò bá fetí sí ọ̀rọ̀ mi, tí ẹ kò ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́, tí ẹ̀ ń ru ẹrù wọ inú Jerusalẹmu lọ́jọ́ ìsinmi, n óo ṣá iná sí ẹnubodè Jerusalẹmu, yóo jó àwọn ààfin rẹ̀, kò sì ní ṣe é pa.’ ” OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀, ó ní: “Dìde, lọ sí ilé amọ̀kòkò, níbẹ̀ ni óo ti gbọ́ ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ bá ọ sọ.” Mo bá lọ sí ilé amọ̀kòkò. Mo bá a tí ó ń mọ ìkòkò kan lórí òkúta tí wọn fi ń mọ ìkòkò. Ìkòkò tí ó ń fi amọ̀ mọ bàjẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ó bá fi amọ̀ náà mọ ìkòkò mìíràn, tí ó wù ú. OLUWA bá sọ fún mi pé, “Ẹ̀yin ilé Israẹli, ṣé n kò lè ṣe yín bí amọ̀kòkò yìí ti ṣe ìkòkò tí ó mọ ni? Bí amọ̀ ti rí lọ́wọ́ amọ̀kòkò ni ẹ rí lọ́wọ́ mi, ẹ̀yin ilé Israẹli. Bí mo bá sọ pé n óo fa orílẹ̀-èdè kan, tabi ìjọba kan tu, n óo wó o lulẹ̀, n óo sì pa á run, bí orílẹ̀-èdè ọ̀hún bá yipada kúrò ninu ìwà burúkú rẹ̀, n óo dá ibi tí mo ti fẹ́ ṣe sí i tẹ́lẹ̀ dúró. Bí mo bá sọ pé n óo gbé orílẹ̀-èdè kan dìde, n óo sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀; bí ó bá ṣe nǹkan burúkú lójú mi, tí kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, n óo dá nǹkan rere tí mo ti fẹ́ ṣe fún un dúró. Nítorí náà, sọ fún àwọn ará Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu pé, èmi OLUWA ní, mò ń pète ibi kan si yín, mo sì ń pinnu rẹ̀ lọ́wọ́ báyìí, kí olukuluku yín yipada kúrò ninu ibi tí ó ń ṣe; kí ẹ sì tún ìwà ati ìṣe yín ṣe. Ṣugbọn wọ́n ń wí pé, ‘Rárá o, OLUWA kàn ń sọ tirẹ̀ ni, tinú wa ni a óo ṣe, olukuluku yóo máa lo agídí ọkàn rẹ̀.’ ” Nítorí náà OLUWA ní, “Ẹ bèèrè láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè, bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ irú rẹ̀ rí. Israẹli ti ṣe ohun tó burú gan-an. Ṣé yìnyín òkè Lẹbanoni a máa dà ní pàlàpálá Sirioni? Àbí omi tútù tí máa ń ṣàn láti inú òkè rẹ̀ a máa gbẹ? Ṣugbọn àwọn eniyan mi ti gbàgbé mi, wọ́n ń sun turari sí oriṣa èké. Wọ́n ti kọsẹ̀ ní ojú ọ̀nà àtijọ́ tí wọn ń tọ̀, wọ́n ti yà sí ọ̀nà ojúgbó tí kì í ṣe ojú ọ̀nà tààrà. Wọ́n sọ ilẹ̀ wọn di ohun ẹ̀rù ati ohun àrípòṣé títí lae. Gbogbo àwọn tí wọn bá gba ibẹ̀ kọjá ni ẹ̀rù yóo máa bà, tí wọn yóo sì máa mi orí. N óo fọ́n wọn ká níwájú ọ̀tá bí ẹ̀fúùfù ìlà oòrùn. Ẹ̀yìn ni n óo kọ sí wọn lọ́jọ́ àjálù, wọn kò ní rí ojú mi.” Wọ́n bá dáhùn pé, “Ẹ wá, kí á gbìmọ̀ ibi sí Jeremaya, nítorí pé òfin kò ní parun lọ́dọ̀ àwọn alufaa, ìmọ̀ràn kò ní tán lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n, ọ̀rọ̀ Ọlọrun kò sì ní ṣàì máa wà lẹ́nu àwọn wolii. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á fi ọ̀rọ̀ ẹnu wa pa á, ẹ má sì jẹ́ kí á fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kankan.” Mo bá gbadura pe, “Tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi, OLUWA, kí o sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi. Ṣé ibi ni eniyan fi í san rere? Sibẹ wọ́n ti wa kòtò sílẹ̀ fún mi. Ranti bí mo ti dúró níwájú rẹ tí mo sọ ọ̀rọ̀ wọn ní rere, kí o baà lè yí ibinu rẹ pada lórí wọn. Nítorí náà ìyàn ni kí ó pa àwọn ọmọ wọn, kí ogun pa wọ́n, kí àwọn aya wọn di aláìlọ́mọ ati opó, kí àjàkálẹ̀ àrùn pa àwọn ọmọkunrin wọn, kí idà ọ̀tá sì pa àwọn ọ̀dọ̀ wọn lójú ogun. Kí igbe ẹkún ó sọ ninu ilé wọn, nígbà tí o bá mú àwọn apanirun wá sórí wọn lójijì; nítorí pé wọ́n wa kòtò láti mú mi, wọ́n dẹ tàkúté sílẹ̀ fún mi. OLUWA, gbogbo àbá tí wọn ń dá ni o mọ̀, o mọ gbogbo ète tí wọn ń pa láti pa mí. Má dárí ìwà ibi wọn jì wọ́n, má sì pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ níwájú rẹ. Jẹ́ kí wọn ṣubú níwájú rẹ, nígbà tí inú bá ń bí ọ ni kí o bá wọn wí.” OLUWA ní kí n lọ ra ìgò amọ̀ kan, kí n mú díẹ̀ ninu àwọn àgbààgbà ìlú ati àwọn bíi mélòó kan ninu àwọn àgbà alufaa, kí n lọ sí ìsàlẹ̀ àfonífojì ọmọ Hinomu, lẹ́nu Ibodè Àpáàdì; kí n sì kéde ọ̀rọ̀ tí òun óo sọ fún mi níbẹ̀: “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ̀yin ọba Juda ati ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní òun óo mú ibi kan wá sórí ilẹ̀ yìí, híhó ni etí gbogbo àwọn tí wọn bá gbọ́ nípa rẹ̀ yóo máa hó. Nítorí pé àwọn eniyan wọnyi ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n ti sọ ibí di aláìmọ́ pẹlu turari tí wọn ń sun sí àwọn oriṣa tí àwọn, ati àwọn baba wọn, ati àwọn ọba Juda kò mọ̀ rí. Wọ́n ti pa àwọn aláìṣẹ̀ sí gbogbo ibí yìí. Wọ́n kọ́ pẹpẹ oriṣa Baali, wọ́n sì ń fi àwọn ọmọkunrin wọn rú ẹbọ sísun sí i. N kò pàṣẹ fún wọn pé kí wọn máa ṣe bẹ́ẹ̀, n kò fún wọn ní irú ìlànà bẹ́ẹ̀; ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀ kò tilẹ̀ wá sí mi lọ́kàn. Nítorí náà, ọjọ́ ń bọ̀, tí a kò ní pe ibí yìí ní Tofeti tabi àfonífojì ọmọ Hinomu mọ́. Àfonífojì ìpànìyàn ni a óo máa pè é. N óo sọ ìmọ̀ àwọn ará Juda ati ti àwọn ará ìlú Jerusalẹmu di òfo, n óo jẹ́ kí àwọn ọ̀tá wọn ati àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí wọn fi idà pa wọ́n. N óo sì fi òkú wọn ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko. N óo sì sọ ìlú yìí di ohun ẹ̀rù ati àrípòṣé, ẹ̀rù ìlú náà yóo sì máa ba gbogbo ẹni tí ó bá kọjá níbẹ̀, wọn yóo máa pòṣé nítorí àjálù tí ó dé bá a. N óo mú kí wọn máa pa ọmọ wọn ọkunrin ati obinrin jẹ. Olukuluku yóo máa pa aládùúgbò rẹ̀ jẹ nítorí ìdààmú tí àwọn ọ̀tá wọn, ati àwọn tí ń wá ẹ̀mí wọn yóo kó bá wọn, nígbà tí ogun bá dótì wọ́n.” OLUWA ní lẹ́yìn náà kí n fọ́ ìgò amọ̀ náà ní ojú àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu mi, kí n sì sọ fún wọn pé, OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Bí ẹni fọ́ ìkòkò amọ̀ ni n óo ṣe fọ́ àwọn eniyan yìí ati ìlú yìí, kò sì ní ní àtúnṣe mọ́. Ní Tofeti ni wọn yóo máa sin òkú sí nígbà tí wọn kò bá rí ààyè sin òkú sí mọ́. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe sí ìlú yìí ati àwọn tí wọn ń gbé ibẹ̀. Bíi Tofeti ni n óo ṣe ìlú náà; Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Àwọn ilé Jerusalẹmu ati àwọn ààfin ọba Juda, gbogbo ilé tí wọn ń sun turari sí àwọn ogun ọ̀run lórí òrùlé wọn, tí wọn sì ti rú ẹbọ ohun mímu sí àwọn oriṣa mìíràn, gbogbo wọn ni yóo di aláìmọ́ bíi Tofeti.” Nígbà tí Jeremaya pada dé láti Tofeti, níbi tí OLUWA rán an lọ pé kí ó lọ sọ àsọtẹ́lẹ̀, ó dúró ní àgbàlá ilé OLUWA, ó sọ fún gbogbo àwọn tí wọ́n péjọ sibẹ pé, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, ‘N óo mú kí ibi tí mo ti kéde rẹ̀ dé bá ìlú yìí ati àwọn ìlú tí wọn yí i ká, nítorí wọ́n ti ṣe oríkunkun, wọn kò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.’ ” Nígbà tí Paṣuri alufaa, ọmọ Imeri, tí ó jẹ́ olórí àwọn olùṣọ́ ilé OLUWA, gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Jeremaya ń sọ, ó ní kí wọn lu Jeremaya, kí wọn kàn ààbà mọ́ ọn lẹ́sẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà Bẹnjamini ti òkè, ní ilé OLUWA. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, nígbà tí Paṣuri tú Jeremaya sílẹ̀ ninu ààbà, Jeremaya wí fún un pé, “Kì í ṣe Paṣuri ni OLUWA pe orúkọ rẹ, ìpayà lọ́tùn-ún ati lósì ni OLUWA pè ọ́. OLUWA ní, ‘N óo sọ ọ́ di ìpayà fún ara rẹ ati fún gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ràn rẹ. Àwọn ọ̀tá yóo fi idà pa wọ́n níṣojú rẹ, n óo fi gbogbo ilẹ̀ Juda lé ọba Babiloni lọ́wọ́. Yóo kó wọn ní ìgbèkùn lọ sí Babiloni, yóo sì fi idà pa wọ́n. Bákan náà, n óo da gbogbo ọrọ̀ ìlú yìí, ati gbogbo èrè iṣẹ́ tí wọ́n ṣe lé àwọn ará Babiloni lọ́wọ́, pẹlu gbogbo nǹkan olówó iyebíye wọn, ati gbogbo ìṣúra àwọn ọba Juda; gbogbo rẹ̀ ni àwọn ọ̀tá wọn, àwọn ará Babiloni yóo fogun kó, wọn yóo sì rù wọ́n lọ sí Babiloni. Ní ti ìwọ Paṣuri, ati gbogbo àwọn ará ilé rẹ, wọn óo ko yín ní ìgbèkùn lọ sí Babiloni. Ibẹ̀ ni ẹ óo kú sí, ibẹ̀ ni wọ́n óo sì sin yín sí; àtìwọ, ati gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí ò ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ fún.’ ” OLUWA, o tàn mí jẹ, mo sì gba ẹ̀tàn; o ní agbára jù mí lọ, o sì borí mi. Mo di ẹni ẹ̀sín láti àárọ̀ títí di alẹ́, gbogbo eniyan ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́. Gbogbo ìgbà tí mo bá ti sọ̀rọ̀, ni mò ń kígbe pé, “Ogun ati ìparun dé!” Nítorí náà, ọ̀rọ̀ OLUWA tí mò ń kéde sọ mí di ẹni yẹ̀yẹ́ tọ̀sán-tòru. Ṣugbọn nígbàkúùgbà tí mo bá wí pé n kò ní dárúkọ rẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ̀ mọ́, ọ̀rọ̀ rẹ a máa jó mi ninu bí iná, a sì máa ro mí ninu egungun. Mo gbìyànjú títí pé kí n pa á mọ́ra, ṣugbọn kò ṣeéṣe. Nítorí mò ń gbọ́ tí ọpọlọpọ ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ pé, “Ìpayà wà lọ́tùn-ún lósì, ẹ lọ fẹjọ́ rẹ̀ sùn. Ẹ jẹ́ kí á fẹjọ́ rẹ̀ sùn.” Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ń wí, tí wọn sì ń retí ìṣubú mi. Wọ́n ń sọ pé, “Bóyá yóo bọ́ sọ́wọ́ ẹlẹ́tàn, ọwọ́ wa yóo sì tẹ̀ ẹ́; a óo sì gbẹ̀san lára rẹ̀.” Ṣugbọn OLUWA wà pẹlu mi bíi jagunjagun tí ó bani lẹ́rù. Nítorí náà àwọn tí wọn ń lépa mi yóo kọsẹ̀, apá wọn kò ní ká mi. Ojú yóo tì wọ́n lọpọlọpọ nítorí wọn kò ní lè borí mi. Ẹ̀sín tí ẹnikẹ́ni kò ní gbàgbé yóo dé bá wọn títí lae. OLUWA àwọn ọmọ ogun, ìwọ tíí dán olódodo wò, ìwọ tí o mọ ọkàn ati èrò eniyan. Gbẹ̀san lára wọn kí n fojú rí i, nítorí ìwọ ni mo fi ọ̀rọ̀ mi lé lọ́wọ́. Ẹ kọrin sí OLUWA, ẹ yin OLUWA. Nítorí pé ó gba ẹ̀mí aláìní sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn aṣebi. Ègún ni fún ọjọ́ tí a bí mi, kí ọjọ́ tí ìyá mi bí mi má jẹ́ ọjọ́ ayọ̀. Ègún ni fún ẹni tí ó yọ̀ fún baba mi, tí ó sọ fún un pé, “Iyawo rẹ ti bí ọmọkunrin kan fún ọ, tí ó mú inú rẹ̀ dùn.” Kí olúwarẹ̀ dàbí àwọn ìlú tí OLUWA parun láìṣàánú wọn. Kí ó gbọ́ igbe lówùúrọ̀, ati ariwo ìdágìrì lọ́sàn-án gangan. Nítorí pé kò pa mí ninu oyún, kí inú ìyá mi lè jẹ́ isà òkú fún mi. Kí n wà ninu oyún ninu ìyá mi títí ayé. Kí ló dé tí wọn bí mi sáyé? Ṣé kí n lè máa fojú rí ìṣẹ́ ati ìbànújẹ́ ni? Kí gbogbo ọjọ́ ayé mi lè kún fún ìtìjú? Ọ̀rọ̀ tí Jeremaya gbọ́ lẹ́nu OLUWA nìyí nígbà tí ọba Sedekaya rán Paṣuri, ọmọ Malikaya, ati alufaa Sefanaya, ọmọ Maaseaya, sí i; tí ọba Sedekaya ní, “Ẹ sọ fún Jeremaya pé kí ó bá wa ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ OLUWA nípa Nebukadinesari, ọba Babiloni, tí ó gbógun tì wá; bóyá OLUWA yóo ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún wa, kí Nebukadinesari kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kúrò ní ilẹ̀ wa.” Jeremaya sọ fun awọn tí wọn rán sí i, kí wọ́n sọ fún Sedekaya pé OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, “N óo gba àwọn ohun ìjà tí ó wà lọ́wọ́ yín, tí ẹ fi ń bá ọba Babiloni ati àwọn ará Kalidea tí wọn gbógun tì yín lẹ́yìn odi jà, n óo dá wọn pada sí ààrin ìlú, n óo sì dojú wọn kọ yín. Èmi fúnra mi ni n óo ba yín jà. Ipá ati agbára, pẹlu ibinu ńlá, ati ìrúnú gbígbóná ni n óo fi ba yín jà. N óo fi àjàkálẹ̀ àrùn ńlá kọlu àwọn ará ìlú yìí, ati eniyan ati ẹranko ni yóo sì kú. Lẹ́yìn náà n óo mú Sedekaya ọba Juda, ati àwọn ìjòyè rẹ̀, ati àwọn tí àjàkálẹ̀ àrùn, ogun, ati ìyàn, bá pa kù ní ìlú yìí, n óo fi wọ́n lé Nebukadinesari, ọba Babiloni lọ́wọ́, òun ati àwọn ọ̀tá tí ń wá ọ̀nà láti pa wọ́n. Ọba Babiloni yóo fi idà pa wọ́n, kò ní ṣàánú wọn, kò sì ní dá ẹnikẹ́ni sí.” OLUWA ní, “Sọ fún àwọn eniyan yìí pé èmi OLUWA ni mo la ọ̀nà meji níwájú wọn: ọ̀nà ìyè ati ọ̀nà ikú. Ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn yóo pa ẹni tí ó bá dúró sinu ìlú yìí; ṣugbọn ẹni tí ó bá jáde tí ó sì fa ara rẹ̀ fún àwọn ará Kalidea, tí ó gbé ogun tì yín, yóo yè, yóo dàbí ẹni tó ja àjàbọ́. Nítorí pé mo ti dójú lé ìlú yìí láti ṣe ní ibi, kì í ṣe fún rere. Ìlú yìí yóo bọ́ sọ́wọ́ ọba Babiloni, yóo sì dá iná sun ún, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA ní kí n sọ fún ìdílé ọba Juda pé òun OLUWA ní, “Ẹ̀yin ará ilé Dafidi! Ẹ máa dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ ní òwúrọ̀, ẹ máa gba ẹni tí a jà lólè lọ́wọ́ aninilára, kí ibinu èmi OLUWA má baà ru jáde, nítorí iṣẹ́ ibi yín, kí ó sì máa jó bíi iná, láìsí ẹni tí yóo lè pa á.” OLUWA ní, “Ẹ wò ó, mo dojú ìjà kọ yín, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé àfonífojì, tí ó dàbí àpáta tí ó yọ sókè ju pẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wí pé, ‘Ta ló lè dojú ìjà kọ wá? Àbí ta ló lè wọ inú odi ìlú wa?’ N óo jẹ yín níyà gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ yín; èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo dáná sun igbó yín, yóo sì jó gbogbo ohun tí ó wà ní agbègbè yín ní àjórun.” OLUWA sọ fún mi pé, kí n lọ sí ilé ọba Juda kí n sọ fún un níbẹ̀ pé, “Gbọ́ ohun tí OLUWA sọ, ìwọ ọba Juda, tí o jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, ìwọ ati àwọn ìjòyè rẹ ati àwọn eniyan rẹ, tí wọn ń gba àwọn ẹnubodè wọnyi wọlé: Ẹ máa ṣe ẹ̀tọ́ ati òdodo, kí ẹ máa gba ẹni tí wọn ń jà lólè lọ́wọ́ àwọn aninilára. Ẹ má hùwà burúkú sí àwọn àlejò, tabi àwọn aláìníbaba, ati àwọn opó. Ẹ má ṣe wọ́n níbi, ẹ má sì ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ibi mímọ́ yìí. Nítorí pé bí ẹ bá fi tọkàntọkàn fetí sí ọ̀rọ̀ mi, àwọn ọba yóo máa wọlé, wọn yóo sì máa jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi. Wọn yóo máa gun ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun àtàwọn, ati àwọn ìjòyè wọn, ati àwọn eniyan. Ṣugbọn bí ẹ kò bá gba ohun tí mo wí, mo ti fi ara mi búra pé ilẹ̀ yìí yóo di ahoro. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA sọ nípa ìdílé ọba Juda pé, “Bíi Gileadi ni o dára lójú mi, ati bí orí òkè Lẹbanoni. Ṣugbọn sibẹ, dájúdájú, n óo sọ ọ́ di aṣálẹ̀; o óo sì di ìlú tí ẹnikẹ́ni kò ní gbé. N óo kó àwọn apanirun tí yóo pa ọ́ run wá, olukuluku yóo wá pẹlu ohun ìjà rẹ̀. Wọn óo gé àwọn tí wọn dára jùlọ ninu àwọn igi Kedari yín, wọn óo sì sun wọ́n níná. “Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ni yóo máa gba ìlú yìí kọjá; wọn yóo sì máa bi ara wọn pé, ‘Kí ló dé tí OLUWA fi ṣe báyìí sí ìlú ńlá yìí?’ Àwọn eniyan yóo sì máa dáhùn pé, ‘Nítorí pé wọ́n kọ majẹmu OLUWA Ọlọrun wọn sílẹ̀ ni, wọ́n ń bọ oriṣa, wọ́n sì ń sìn wọ́n.’ ” Ẹ̀yin ará Juda, ẹ má sọkún nítorí ọba tí ó kú, ẹ má sì dárò rẹ̀. Ọba tí ń lọ sí ìgbèkùn ni kí ẹ sọkún fún, nítorí pé yóo lọ, kò sì ní pada wá mọ́ láti fojú kan ilẹ̀ tí a bí i sí. Nítorí pé OLUWA sọ nípa Joahasi, ọba Juda, ọmọ Josaya, tí ó jọba dípò Josaya baba rẹ̀, tí ó sì jáde kúrò ní ibí yìí pé, “Kò ní pada sibẹ mọ́. Ibi tí wọn mú un ní ìgbèkùn lọ ni yóo kú sí; kò ní fi ojú rí ilẹ̀ yìí mọ́.” Ẹni tí ó ń fi aiṣododo kọ́ ilé rẹ̀ gbé, tí ó ń fi ọ̀nà èrú kọ́ òrùlé rẹ̀. Tí ó mú ọmọ ẹnìkejì rẹ̀ sìn lọ́fẹ̀ẹ́, láìsan owó iṣẹ́ rẹ̀ fún un. Ègbé ni fún ẹni tí ó wí pé, “N óo kọ́ ilé ńlá fún ara mi, ilé tí ó ní yàrá ńláńlá lókè rẹ̀.” Ó bá yọ àwọn fèrèsé sí i lẹ́gbẹ̀ẹ́. Ó fi igi kedari bo ara ògiri rẹ̀, ó wá fi ọ̀dà pupa kùn ún. Ṣé ilé kedari tí o kọ́ ni ó sọ ọ́ di ọba? Wo baba rẹ, ṣé kò rí jẹ ni, tabi kò rí mu? Ṣebí ó ṣe ẹ̀tọ́ ati òdodo, ṣebí ó sì dára fún un. Ẹjọ́ ẹ̀tọ́ níí dá fún talaka ati aláìní, ohun gbogbo sì ń lọ dáradára. Ṣebí èyí ni à ń pè ní kí eniyan mọ OLUWA? OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. Ṣugbọn níbi èrè aiṣododo nìkan ni ojú ati ọkàn yín ń wà, níbi kí ẹ máa pa aláìṣẹ̀, kí ẹ máa ni eniyan lára, kí ẹ sì máa hùwà ìkà. Nítorí náà, OLUWA sọ nípa Jehoiakimu, ọba Juda, ọmọ Josaya pé, wọn kò ní dárò rẹ̀, pé, “Ó ṣe, arakunrin mi!” Tabi pé, “Ó ṣe, arabinrin mi!” Wọn kò ní ké pé, “Ó ṣe, oluwa mi!” Tabi pé, “Ó ṣe! Áà! Kabiyesi!” Bí ẹni ń ṣe òkú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni wọ́n óo ṣe òkú rẹ̀; ẹ̀yìn odi Jerusalẹmu ni wọn yóo wọ́ ọ jù sí. Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ẹ gun orí òkè Lẹbanoni lọ, kí ẹ kígbe. Ẹ dúró lórí òkè Baṣani, kí ẹ pariwo gidigidi, ẹ kígbe láti orí òkè Abarimu, nítorí pé a ti pa gbogbo àwọn alájọṣe yín run. OLUWA bá yín sọ̀rọ̀ nígbà tí nǹkan ń dára fun yín, ṣugbọn ẹ sọ pé ẹ kò ní gbọ́. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ tí ń ṣe láti kékeré yín, ẹ kì í gbọ́rọ̀ sí OLUWA lẹ́nu. Afẹ́fẹ́ yóo fẹ́ gbogbo àwọn olórí yín lọ, àwọn olólùfẹ́ yín yóo lọ sí ìgbèkùn. Ojú yóo wá tì yín, ẹ óo sì di ẹni ẹ̀tẹ́, nítorí gbogbo ibi tí ẹ̀ ń ṣe. Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Lẹbanoni, tí ẹ kọ́ ilé yín sí ààrin igi kedari. Ẹ óo kérora nígbà tí ara bá ń ni yín, tí ara ń ni yín bíi ti obinrin tí ń rọbí ọmọ! OLUWA sọ fún Jehoiakini ọba, ọmọ Jehoiakimu, ọba Juda, pé, “Mo fi ara mi búra, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Bí ó bá tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ ni òrùka èdìdì ọwọ́ ọ̀tún mi, n óo bọ́ ọ kúrò, n óo sì fi ọ́ lé Nebukadinesari ọba Babiloni, ati àwọn ará Kalidea lọ́wọ́, àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí rẹ, tí ẹ̀rù wọn sì ń bà ọ́. N óo wọ́ ìwọ ati ìyá tí ó bí ọ jù sí ilẹ̀ àjèjì, tí kì í ṣe ibi tí wọ́n bí ọ sí, ibẹ̀ ni ẹ óo kú sí. Ṣugbọn ilẹ̀ tí ọkàn yín fẹ́ pada sí, ẹ kò ní pada sibẹ mọ́.” Ṣé àfọ́kù ìkòkò tí ẹnikẹ́ni kò kà kún ni Jehoiakini? Àbí o ti di ohun èlò àlòpatì? Kí ló dé tí òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ fi di ẹni tí a kó lẹ́rú lọ sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀ rí? Ilẹ̀! Ilẹ̀! Gbọ́ ohun tí OLUWA sọ! Ó ní, “Ẹ kọ orúkọ ọkunrin yìí sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́mọ, ẹni tí kò ní ṣe rere kan ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀; nítorí pé kò sí ọ̀kankan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ tí yóo rọ́pò rẹ̀ lórí ìtẹ́ Dafidi, Ìdílé rẹ̀ kò sì ní jọba mọ ní Juda.” OLUWA ní, “Àwọn olùṣọ́-aguntan tí wọn ń tú àwọn agbo aguntan mi ká, tí wọn ń run wọ́n gbé!” Nítorí náà, OLUWA, Ọlọrun Israẹli sọ nípa àwọn tí ó fi ṣọ́ àwọn eniyan rẹ̀, láti máa bojútó wọn pé, “Ẹ ti tú àwọn aguntan mi ká, ẹ ti lé wọn dànù, ẹ kò sì tọ́jú wọn. N óo wá ṣe ìdájọ́ fun yín nítorí iṣẹ́ ibi yín, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo kó àwọn tí wọ́n kù ninu àwọn aguntan mi jọ láti gbogbo ibi tí mo lé wọn lọ. N óo kó wọn pada sinu agbo wọn. Wọn óo bímọ lémọ, wọn óo sì máa pọ̀ sí i. N óo wá fún wọn ní olùṣọ́ mìíràn tí yóo tọ́jú wọn. Ẹ̀rù kò ní bà wọ́n mọ́, wọn kò ní fòyà, ọ̀kankan ninu wọn kò sì ní sọnù, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “Wò ó! Àkókò kan ń bọ̀, tí n óo gbé Ẹ̀ka olódodo kan dìde ninu ìdílé Dafidi. Yóo jọba, yóo hùwà ọlọ́gbọ́n, yóo sì ṣe ẹ̀tọ́ ati òdodo ní ilẹ̀ náà. Juda yóo rí ìgbàlà ní ìgbà tirẹ̀, Israẹli yóo sì wà láìléwu. Orúkọ tí a óo máa pè é ni ‘OLUWA ni òdodo wa.’ “Nítorí náà àkókò kan ń bọ̀, tí wọn kò ní máa búra ní orúkọ OLUWA tí ó kó àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti mọ́, ṣugbọn tí wọn yóo máa wí pé, ‘Ní orúkọ OLUWA tí ó kó àwọn ọmọ ilé Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ àríwá, ati gbogbo ilẹ̀ tí wọn kó wọn lẹ́rú lọ, tí ó sì mú wọn pada sí ilẹ̀ wọn.’ Wọn óo wá máa gbé orí ilẹ̀ wọn nígbà náà. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” Ọkàn mi bàjẹ́ nítorí àwọn wolii, gbogbo ara mi ń gbọ̀n. Mo dàbí ọ̀mùtí tí ó ti mu ọtí yó, mo dàbí ẹni tí ọtí ń pa, nítorí OLUWA, ati nítorí ọ̀rọ̀ mímọ́ rẹ̀. Nítorí pé ilẹ̀ náà kún fún àgbèrè ẹ̀sìn, ọ̀nà ibi ni wọ́n ń tọ̀, wọn kò sì lo agbára wọn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ nítorí ègún, ilẹ̀ ti di gbígbẹ gbogbo pápá oko ló ti gbẹ. Ati wolii, ati alufaa, ìwà burúkú ni wọ́n ń hù, ní ilé mi pàápàá mo rí iṣẹ́ ibi wọn, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Nítorí náà ọ̀nà wọn yóo dàbí ọ̀nà tí ń yọ̀ ninu òkùnkùn, a óo tì wọ́n sinu rẹ̀, wọn yóo sì ṣubú, nítorí n óo mú kí ibi bá wọn ní ọdún ìjìyà wọn. Mo rí nǹkankan tí ó burú lọ́wọ́ àwọn wolii Samaria: Ẹ̀mí oriṣa Baali ni wọ́n fi ń sọ àsọtẹ́lẹ̀; wọ́n sì ń ṣi àwọn ọmọ Israẹli, eniyan mi, lọ́nà. Mo rí nǹkankan tí ó bani lẹ́rù lọ́wọ́ àwọn wolii Jerusalẹmu: Wọ́n ń ṣe àgbèrè ẹ̀sìn, wọ́n ń hùwà èké; wọ́n ń ran àwọn ẹni ibi lọ́wọ́, kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni yipada kúrò ninu iṣẹ́ ibi rẹ̀. Gbogbo wọn ti di ará Sodomu lójú mi, àwọn ará Jerusalẹmu sì dàbí àwọn ará Gomora. Nítorí náà OLUWA àwọn ọmọ ogun sọ nípa àwọn wolii pé: N óo fún wọn ní ewé igi kíkorò jẹ, n óo fún wọn ní omi májèlé mu. Nítorí pé láti ọ̀dọ̀ àwọn wolii Jerusalẹmu ni ìwà burúkú ti tàn ká gbogbo ilẹ̀ yìí. OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wolii tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun yín, tí wọ́n ń mu yín gbẹ́kẹ̀lé irọ́. Ohun tí wọn fẹ́ lọ́kàn wọn ni wọ́n ń sọ, kì í ṣe ẹnu èmi OLUWA ni wọ́n ti gbọ́ ọ. Wọ́n ń sọ lemọ́lemọ́ fún àwọn tí wọn kò ka ọ̀rọ̀ OLUWA sí pé, yóo dára fún wọn. Wọ́n ń wí fún gbogbo àwọn tí wọn ń tẹ̀lé àìgbọràn ọkàn wọn pé ibi kò ní bá wọn.” Mo ní, “Èwo ninu wọn ló wà ninu ìgbìmọ̀ OLUWA tí ó ti ṣe akiyesi tí ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀? Èwo ninu wọn ni ó fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó sì gbà á gbọ́? Ẹ wo ibinu OLUWA bí ó ṣe ń jà bí ìjì! Ó ti fa ibinu yọ. Ó sì ń jà bí ìjì líle. Yóo tú dà sí orí àwọn eniyan burúkú. Inú OLUWA kò ní rọ̀ títí yóo fi ṣe ohun tí ó pinnu lọ́kàn rẹ̀. Yóo ye wọn nígbà tí ọjọ́ ìkẹyìn bá dé.” OLUWA ní, “N kò rán àwọn wolii níṣẹ́, sibẹsibẹ aré ni wọ́n ń sá lọ jíṣẹ́. N kò bá wọn sọ̀rọ̀, sibẹsibẹ wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀. Bí wọn bá ti bá mi pé ní ìgbìmọ̀ ni, wọn ìbá kéde ọ̀rọ̀ mi fún àwọn eniyan mi, wọn ìbá yí wọn pada kúrò lọ́nà ibi tí wọn ń rìn, ati iṣẹ́ ibi tí wọn ń ṣe. “Ṣé nítòsí nìkan ni mo ti jẹ́ Ọlọrun ni, èmi kì í ṣe Ọlọrun ọ̀nà jíjìn? Ǹjẹ́ ẹnìkan lè sápamọ́ sí ìkọ̀kọ̀ kan tí n kò fi ní rí i? Kì í ṣe èmi ni mo wà ní gbogbo ọ̀run tí mo sì tún wà ní gbogbo ayé? Mo gbọ́ ohun tí àwọn wolii tí wọn ń fi orúkọ mi sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ń sọ, tí wọn ń sọ pé, àwọn lá àlá, àwọn lá àlá! Irọ́ yóo ti pẹ́ tó lọ́kàn àwọn wolii èké tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ẹ̀tàn. Wọ́n ṣebí àwọn lè fi àlá tí olukuluku wọn ń rọ́ fún ẹnìkejì rẹ̀ mú àwọn eniyan mi gbàgbé orúkọ mi, bí àwọn baba wọn ṣe gbàgbé mi, tí wọn ń tẹ̀lé oriṣa Baali. Kí àwọn wolii tí wọn lá àlá máa rọ́ àlá wọn, ṣugbọn ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí ó sọ ọ́ pẹlu òtítọ́. Báwo ni a ṣe lè fi ìyàngbò wé ọkà? Ṣebí bí iná ni ọ̀rọ̀ mi rí, ati bí òòlù irin tíí fọ́ àpáta sí wẹ́wẹ́? Nítorí náà, mo dojú ìjà kọ àwọn wolii tí wọn ń sọ ọ̀rọ̀ tí wọn gbọ́ lẹ́nu ara wọn, tí wọn ń sọ pé èmi ni mo sọ ọ́. Mo lòdì sí àwọn wolii tí wọn ń sọ ọ̀rọ̀ ti ara wọn, tí wọn ń sọ pé èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Mo lòdì sí àwọn wolii tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ àlá irọ́, tí wọn ń rọ́ àlá irọ́ wọn, tí wọn fí ń ṣi àwọn eniyan mi lọ́nà pẹlu irọ́ ati ìṣekúṣe wọn, nígbà tí n kò rán wọn níṣẹ́, tí n kò sì fún wọn láṣẹ. Nítorí náà wọn kò ṣe àwọn eniyan wọnyi ní anfaani kankan. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” Bí ọ̀kan ninu àwọn eniyan wọnyi, tabi wolii kan, tabi alufaa kan, bá bi ọ́ léèrè pé, “Kí ni iṣẹ́ tí OLUWA rán?” Wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin gan-an ni ẹ jẹ́ ẹrù. OLUWA sì ní òun óo gbé yín sọnù.” Bí wolii kan tabi alufaa kan tabi ẹnikẹ́ni ninu àwọn eniyan wọnyi bá wí pé òun ń jẹ́ iṣẹ́ OLUWA, n óo jẹ olúwarẹ̀ ati ilé rẹ̀ níyà. Báyìí ni kí ẹnìkọ̀ọ̀kan máa wí fún ẹnìkejì rẹ, ati fún arakunrin rẹ̀, “Kí ni ìdáhùn OLUWA?” tabi “Kí ni OLUWA wí?” Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ mẹ́nuba ẹrù OLUWA mọ́. Nítorí pé èrò ọkàn olukuluku ni ẹrù OLUWA lójú ara rẹ̀; ẹ sì ń yí ọ̀rọ̀ Ọlọrun alààyè po, ọ̀rọ̀ OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun wa. Bí ẹ óo ti máa bèèrè lọ́wọ́ àwọn wolii ni pé, “Kí ni ìdáhùn tí OLUWA fún ọ?” Tabi, “Kí ni OLUWA wí?” Ṣugbọn bí ẹ bá mẹ́nu ba “Ẹrù OLUWA,” lẹ́yìn tí mo ti ranṣẹ si yín pé ẹ kò gbọdọ̀ mẹ́nu bà á mọ́, tìtorí rẹ̀, n óo sọ yín sókè, n óo sì gbe yín sọnù kúrò níwájú mi, àtẹ̀yin, àtìlú tí mo fi fún ẹ̀yin, ati àwọn baba ńlá yín. N óo mú ẹ̀gàn ati ẹ̀sín ba yín, tí ẹ kò ní gbàgbé títí ayérayé. Lẹ́yìn tí Nebukadinesari, ọba Babiloni ti kó Jehoiakini ọba Juda, ọmọ Jehoiakimu kúrò ní ìlú Jerusalẹmu lọ sí Babiloni, pẹlu àwọn ìjòyè Juda, ati àwọn oníṣẹ́ ọnà, ati àwọn alágbẹ̀dẹ, OLUWA fi ìran yìí hàn mí. Mo rí apẹ̀rẹ̀ èso ọ̀pọ̀tọ́ meji níwájú ilé OLUWA. Èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó wà ninu apẹ̀rẹ̀ kinni dára gbáà, ó dàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó kọ́kọ́ pọ́n. Èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó wà ninu apẹ̀rẹ̀ keji ti rà patapata tóbẹ́ẹ̀ tí kò ṣe é jẹ. p OLUWA bá bi mí pé, “Jeremaya, kí ni o rí?” Mo ní, “Èso ọ̀pọ̀tọ́ ni, àwọn tí ó dára, dára gan-an, àwọn tí kò sì dára bàjẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ṣe é jẹ.” OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun Israẹli sọ nípa àwọn ará Juda tí wọ́n wà ní ìgbèkùn, àwọn tí mo ti mú kí á kó lẹ́rú láti ibí yìí lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kalidea, ni pé, n óo kà wọ́n sí rere gẹ́gẹ́ bí àwọn èso ọ̀pọ̀tọ́ dáradára wọnyi. N óo fi ojurere wò wọ́n, n óo kó wọn pada wá sí ilẹ̀ yìí. N óo fìdí wọn múlẹ̀, n kò sì ní pa wọ́n run. N óo gbé wọn ró, n kò ní fà wọ́n tu, n óo sì fún wọn ní òye láti mọ̀ pé èmi ni OLUWA. Wọn yóo jẹ́ eniyan mi, èmi náà óo sì jẹ́ Ọlọrun wọn; nítorí tí wọn yóo fi tọkàntọkàn yipada sí mi.” Ṣugbọn ohun tí OLUWA sọ nípa Sedekaya ọba Juda, ati àwọn ìjòyè rẹ̀, ati àwọn ará Jerusalẹmu tí wọ́n kù ní ilẹ̀ yìí, ati àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ Ijipti, ni pé òun óo ṣe wọ́n bí èso burúkú tí kò ṣe é jẹ. Ó ní òun óo sọ wọ́n di ẹni àríbẹ̀rù fún gbogbo ìjọba ayé. Wọn óo di ẹni ẹ̀gàn, ẹni ẹ̀sín, ẹni yẹ̀yẹ́ ati ẹni tí a fi ń ṣẹ́ èpè ní gbogbo ibi tí òun óo tì wọ́n lọ. Ó ní òun óo rán ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn sí wọn, títí wọn yóo fi kú tán, tí kò ní ku ẹyọ ẹnìkan lórí ilẹ̀ tí òun fún àwọn ati àwọn baba ńlá wọn. Ní ọdún kẹrin tí Jehoiakimu, ọmọ Josaya jọba ní Juda, tí ó jẹ́ ọdún kinni tí Nebukadinesari jọba Babiloni, Jeremaya wolii gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA nípa gbogbo àwọn ará Juda. Jeremaya sọ ọ̀rọ̀ náà fún gbogbo àwọn ará Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu. Ó ní, “Fún ọdún mẹtalelogun, láti ọdún kẹtala tí Josaya ọmọ Amoni ti jọba Juda, títí di ọjọ́ òní, ni OLUWA ti ń bá mi sọ̀rọ̀, tí mo sì ti ń sọ ọ́ fun yín lemọ́lemọ́, ṣugbọn tí ẹ kò sì gbọ́. Ẹ kò fetí sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà gbogbo ni OLUWA ń rán àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀, si yín, tí wọn ń sọ fun yín pé kí olukuluku yín yipada kúrò ní ọ̀nà burúkú rẹ̀ ati iṣẹ́ ibi tí ó ń ṣe, kí ẹ lè máa gbé ilẹ̀ tí OLUWA fún ẹ̀yin ati àwọn baba ńlá yín títí lae, láti ìgbà àtijọ́. Wọ́n ní kí ẹ má wá àwọn oriṣa lọ, kí ẹ má bọ wọ́n, kí ẹ má sì sìn wọ́n. Wọ́n ní kí ẹ má fi iṣẹ́ ọwọ́ yín mú un bínú, kí ó má baà ṣe yín ní ibi.” OLUWA alára ní, “Mo wí, ṣugbọn ẹ kò gbọ́ tèmi; kí ẹ lè fi iṣẹ́ ọwọ́ yín mú mi bínú, fún ìpalára ara yín.” Ó ní, “Nítorí pé ẹ kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, n óo ranṣẹ lọ kó gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àríwá wá. N óo ranṣẹ sí Nebukadinesari ọba Babiloni, iranṣẹ mi, n óo jẹ́ kí wọn wá dó ti ilẹ̀ yìí, ati àwọn tí ń gbé ibẹ̀. Gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó wà ní agbègbè ilẹ̀ yìí ni n óo parun patapata, tí n óo sọ di àríbẹ̀rù, ati àrípòṣé, ati ohun ẹ̀gàn títí lae. N óo pa ìró ayọ̀ ati ẹ̀rín rẹ́ láàrin wọn, ẹnìkan kò sì ní gbọ́ ohùn ọkọ iyawo ati ohùn iyawo tuntun mọ́. A kò ní gbọ́ ìró ọlọ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí iná fìtílà mọ́. Gbogbo ilẹ̀ yìí yóo di àlàpà ati aṣálẹ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi yóo sì sin ọba Babiloni fún aadọrin ọdún. Nígbà tí aadọrin ọdún bá pé, n óo jẹ ọba Babiloni ati orílẹ̀-èdè rẹ̀, ati ilẹ̀ àwọn ará Kalidea níyà, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. N óo sì sọ ibẹ̀ di àlàpà títí ayé. N óo mú gbogbo ọ̀rọ̀ burúkú tí mo ti sọ nípa ilẹ̀ náà ṣẹ, ati gbogbo ohun tí a kọ sinu ìwé yìí, àní àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Jeremaya sọ nípa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè. Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ati àwọn ọba alágbára yóo sọ àwọn ará Babiloni pàápàá di ẹrú, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀san ìṣe wọn ati iṣẹ́ ọwọ́ wọn.” OLUWA Ọlọrun Israẹli sọ fún mi pé, “Gba ife ọtí ibinu yìí lọ́wọ́ mi, kí o fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí n óo rán ọ sí mu. Wọn yóo mu ún, wọn yóo sì máa ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n, wọn yóo máa ṣe bí aṣiwèrè nítorí ogun tí n óo rán sí ààrin wọn.” Mo bá gba ife náà lọ́wọ́ OLUWA, mo sì fún gbogbo orílẹ̀-èdè tí OLUWA rán mi sí mu: Jerusalẹmu ati àwọn ìlú Juda, àwọn ọba ilẹ̀ Juda ati àwọn ìjòyè wọn, kí wọn lè di ahoro ati òkítì àlàpà, nǹkan àrípòṣé ati ohun tí à ń fi í ṣépè, bí ó ti rí ní òní yìí. N óo fún Farao, ọba Ijipti mu, ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati àwọn ìjòyè rẹ̀, ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ ati àwọn àlejò tí wọ́n wà láàrin wọn. N óo fún gbogbo àwọn ọba Usi mu, ati gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Filistini, (Aṣikeloni, Gasa, Ekironi ati àwọn tí wọ́n kù ní Aṣidodu). N óo fún Edomu mu, ati Moabu, ati àwọn ọmọ Amoni; ati gbogbo àwọn ọba Tire, ati àwọn ọba Sidoni, ati gbogbo àwọn ọba erékùṣù tí ó wà ní òdìkejì òkun. N óo fún Dedani mu, ati Tema, ati Busi ati gbogbo àwọn tí wọn ń gé ẹsẹ̀ irun wọn. N óo fún gbogbo àwọn ọba Arabia mu ati gbogbo àwọn ọba oríṣìíríṣìí ẹ̀yà tí wọn ń gbé aṣálẹ̀. N óo fún gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Simiri mu, ati gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Elamu ati gbogbo àwọn ti ilẹ̀ Media; ati gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ àríwá, ati àwọn tí wọ́n wà nítòsí, ati àwọn tí wọ́n wà lọ́nà jíjìn. N óo sì fún àwọn ìjọba gbogbo ilẹ̀ ayé mu pẹlu. Lẹ́yìn tí gbogbo wọn bá ti mu tiwọn tán, ọba Babiloni yóo wá mu tirẹ̀. OLUWA ní kí n sọ fún wọn pé, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní kí ẹ mu ọtí kí ẹ yó, kí ẹ sì máa bì, ẹ ṣubú lulẹ̀ kí ẹ má dìde mọ́; nítorí ogun tí n óo jẹ́ kí ó bẹ́ sílẹ̀ ní ààrin yín. Bí wọn bá kọ̀ tí wọn kò gba ife náà lọ́wọ́ rẹ kí wọ́n sì mu ún, wí fún wọn pé, OLUWA àwọn ọmọ ogun ní wọ́n gbọdọ̀ mu ún ni! Nítorí pé mo ti bẹ̀rẹ̀ sí mú kí ibi ṣẹlẹ̀ sórí ìlú tí à ń fi orúkọ mi pè yìí, ǹjẹ́ ẹ lè lọ láìjìyà bí? Rárá o, ẹ kò ní lọ láìjìyà nítorí pé mo ti pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn tí wọn ń gbé orí ilẹ̀ ayé kú ikú idà, èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “Nítorí náà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí fún wọn pé: ‘OLUWA yóo bú ramúramù láti òkè, yóo pariwo láti ibi mímọ́ rẹ̀. Yóo bú ramúramù mọ́ àwọn eniyan inú agbo rẹ̀. Yóo kígbe mọ́ gbogbo aráyé bí igbe àwọn tí ń tẹ àjàrà. Ariwo náà yóo kàn dé òpin ayé, nítorí pé OLUWA ní ẹjọ́ láti bá àwọn orílẹ̀-èdè rò. Yóo dá gbogbo eniyan lẹ́jọ́, yóo fi idà pa àwọn eniyan burúkú, OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.’ ” OLUWA àwọn ọmọ ogun ní ibi yóo máa ṣẹlẹ̀ láti orílẹ̀-èdè kan dé ekeji, ìjì ńlá yóo sì jà láti òpin ayé wá. Òkú àwọn tí OLUWA yóo pa ní ọjọ́ náà yóo kún inú ayé láti òpin kan dé ekeji. Ẹnikẹ́ni kò ní ṣọ̀fọ̀ wọn, kò sí ẹni tí yóo gbé òkú wọn nílẹ̀; wọn kò ní sin wọ́n. Wọn yóo dàbí ìgbẹ́ lórí ilẹ̀. Ẹ̀yin olùṣọ́-aguntan, ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ kígbe. Ẹ̀yin oluwa àwọn agbo ẹran, ẹ máa yíra mọ́lẹ̀ ninu eérú nítorí àkókò tí a óo pa yín, tí a óo sì tu yín ká ti tó, ẹ óo sì ṣubú lulẹ̀ bí ẹran àbọ́pa. Kò ní sí ààbò mọ́ fún àwọn olùṣọ́-aguntan, kò ní sí ọ̀nà ati sá àsálà fún àwọn oluwa àwọn agbo ẹran. Ẹ gbọ́ igbe àwọn olùṣọ́-aguntan ati ẹkún ẹ̀dùn ti àwọn oluwa agbo ẹran; nítorí OLUWA ń ba ibùjẹ ẹran wọn jẹ́. Pápá oko tútù tí ìbẹ̀rù kò sí níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ ti di ahoro nítorí ibinu gbígbóná OLUWA. Bíi kinniun tí ó fi ihò rẹ̀ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA fi àwọn eniyan rẹ̀ sílẹ̀, ilẹ̀ wọn sì ti di ahoro nítorí idà apanirun ati ibinu gbígbóná OLUWA. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Jehoiakimu ọba Juda, ọmọ Josaya, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀; ó ní, “Dúró sí gbọ̀ngàn ilé OLUWA, kí o sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo pa láṣẹ fún ọ pé kí o sọ fún gbogbo àwọn ará ìlú Juda tí wọn ń wá jọ́sìn níbẹ̀. Má fi ọ̀rọ̀ kankan pamọ́. Ó ṣeéṣe kí wọ́n gbọ́, kí olukuluku wọn sì yipada kúrò ní ọ̀nà ibi rẹ̀; kí n lè yí ọkàn mi pada nípa ibi tí mo fẹ́ ṣe sí wọn nítorí iṣẹ́ burúkú wọn. “Sọ fún wọn pé, èmi OLUWA ní bí wọn kò bá fetí sí ọ̀rọ̀ mi, kí wọn máa pa òfin tí mo gbé kalẹ̀ fún wọn mọ́, kí wọn sì máa gbọ́ràn sí àwọn iranṣẹ mi lẹ́nu, ati àwọn wolii mi tí mò ń rán sí wọn léraléra, bí wọn kò tilẹ̀ kà wọ́n sí, nítorí náà ni n óo ṣe ṣe ilé yìí bí mo ti ṣe Ṣilo; n óo sì sọ ìlú yìí di ohun tí gbogbo orílẹ̀-èdè ayé yóo máa fi gégùn-ún.” Àwọn alufaa, àwọn wolii ati gbogbo àwọn eniyan gbọ́ tí Jeremaya ń sọ ọ̀rọ̀ yìí ní ilé OLUWA. Nígbà tí ó sọ gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún un pé kí ó sọ fún gbogbo àwọn eniyan náà tán, gbogbo wọn rá a mú, wọ́n ní, “Kíkú ni o óo kú! Kí ló dé tí o fi sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ OLUWA pé ‘Ilé yìí yóo dàbí Ṣilo, ati pé ìlú yìí yóo di ahoro, ẹnikẹ́ni kò sì ní gbébẹ̀ mọ́?’ ” Gbogbo eniyan bá pé lé Jeremaya lórí ninu ilé OLUWA. Nígbà tí àwọn ìjòyè Juda gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n lọ sí ilé OLUWA láti ààfin ọba, wọ́n sì jókòó ní Ẹnu Ọ̀nà Titun tí ó wà ní ilé OLUWA. Àwọn alufaa ati àwọn wolii bá sọ fún àwọn ìjòyè ati gbogbo àwọn eniyan pé, “Ẹjọ́ ikú ni ó yẹ kí a dá fún ọkunrin yìí nítorí àsọtẹ́lẹ̀ tí ó ń sọ nípa ìlú yìí, ẹ̀yin náà sá fi etí ara yín gbọ́.” Jeremaya bá sọ fún àwọn ìjòyè ati gbogbo àwọn eniyan pé, “OLUWA ni ó rán mi láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ tí ẹ gbọ́ sí ilé yìí ati ìlú yìí. Nítorí náà, ẹ tún ọ̀nà yín ṣe, ẹ pa ìṣe yín dà, kí ẹ sì gbọ́ràn sí OLUWA Ọlọrun yín lẹ́nu, yóo sì yí ọkàn rẹ̀ pada kúrò ninu ibi tí ó sọ pé òun yóo ṣe sí i yín. Ní tèmi, mo wà lọ́wọ́ yín, ohun tí ó bá dára lójú yín ni kí ẹ fi mí ṣe. Ṣugbọn kí ẹ mọ̀ dájú pé bí ẹ bá pa mí, ẹ óo fa ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sórí ara yín, ati ìlú yìí ati àwọn ará ìlú yìí, nítorí pé nítòótọ́ ni OLUWA rán mi pé kí n sọ gbogbo ohun tí mo sọ kí ẹ gbọ́.” Àwọn ìjòyè ati gbogbo àwọn eniyan bá sọ fún àwọn alufaa ati àwọn wolii pé, “Ẹjọ́ ikú kò tọ́ sí ọkunrin yìí, nítorí pé orúkọ OLUWA Ọlọrun wa ni ó fi ń bá wa sọ̀rọ̀.” Àwọn kan ninu àwọn àgbààgbà ìlú dìde, wọ́n bá gbogbo ìjọ eniyan sọ̀rọ̀; wọ́n ní, “Ní ìgbà Hesekaya ọba Juda, Mika ará Moreṣeti sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún gbogbo àwọn ará Juda pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, ‘A óo kọ Sioni bí ilẹ̀ oko, Jerusalẹmu yóo di òkítì àlàpà; òkè ilé yìí yóo sì di igbó kìjikìji.’ Ǹjẹ́ Hesekaya ati gbogbo eniyan Juda pa Mika bí? Ṣebí OLUWA yí ibi tí ó ti pinnu láti ṣe sí wọn pada, nítorí pé Hesekaya bẹ̀rù OLUWA ó sì wá ojurere rẹ̀. Ṣugbọn ní tiwa ibi ńláńlá ni a fẹ́ fà lé orí ara wa yìí.” Ọkunrin kan tún wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Uraya, ọmọ Ṣemaaya, láti ìlú Kiriati Jearimu. Òun náà sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ yìí ati ilẹ̀ wa bí Jeremaya ti sọ yìí. Nígbà tí ọba Jehoiakimu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ati àwọn ìjòyè gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ọba wá ọ̀nà láti pa á. Nígbà tí Uraya gbọ́, ẹ̀rù bà á, ó sì sálọ sí ilẹ̀ Ijipti. Ṣugbọn ọba Jehoiakimu rán Elinatani, ọmọ Akibori, ati àwọn ọkunrin kan lọ sí Ijipti, wọ́n mú Uraya jáde ní ilẹ̀ Ijipti, wọ́n mú un tọ ọba Jehoiakimu wá. Ọba Jehoiakimu fi idà pa á, ó sì ju òkú rẹ̀ sí ibi tí wọn ń sin àwọn talaka sí. Ṣugbọn Ahikamu ọmọ Ṣafani fọwọ́ sí ọ̀rọ̀ mi, kò sì jẹ́ kí á fà mí lé àwọn eniyan lọ́wọ́ láti pa. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekaya, ọba Juda, ọmọ Josaya, OLUWA bá èmi Jeremaya sọ̀rọ̀; ó ní: “Ṣe àjàgà kan pẹlu okùn rẹ̀ kí o sì fi bọ ara rẹ lọ́rùn. Àwọn ikọ̀ kan wá sí ọ̀dọ̀ Sedekaya, ọba Juda, ní Jerusalẹmu, láti ọ̀dọ̀ ọba Edomu ati ọba Moabu, ọba àwọn ọmọ Amoni, ọba Tire, ati ọba Sidoni wá, rán wọn pada sí àwọn oluwa wọn, sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n sọ fún wọn pé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní òun ni òun fi agbára ńlá òun dá ayé: ati eniyan ati ẹranko tí wọ́n wà lórí ilẹ̀; ẹni tí ó bá tọ́ lójú òun ni òun óo sì fi wọ́n fún. Ó ní òun ti fún Nebukadinesari, ọba Babiloni iranṣẹ òun, ní gbogbo àwọn ilẹ̀ wọnyi, òun sì ti fún un ni àwọn ẹranko inú igbó kí wọn máa ṣe iranṣẹ rẹ̀. Gbogbo orílẹ̀-èdè ni yóo máa ṣe ẹrú òun ati ọmọ rẹ̀, ati ọmọ ọmọ rẹ̀, títí àkókò tí ilẹ̀ òun pàápàá yóo fi tó, tí ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ati àwọn ọba ńláńlá yóo sì kó o lẹ́rú.” OLUWA ní, “Ṣugbọn bí orílẹ̀-èdè tabi ìjọba kan bá kọ̀, tí wọn kò sin Nebukadinesari, ọba Babiloni, tí wọn kò sì ti ọrùn wọn bọ àjàgà rẹ̀, ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn ni n óo fi jẹ orílẹ̀-èdè náà níyà títí n óo fi fà á lé ọba Babiloni lọ́wọ́. Nítorí náà, ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wolii yín, ati àwọn awoṣẹ́ yín, àwọn alálàá yín ati àwọn aláfọ̀ṣẹ yín, ati àwọn oṣó yín, tí wọn ń sọ fun yín pé ẹ kò ní di ẹrú ọba Babiloni. Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fun yín, wọ́n fẹ́ kí á ko yín jìnnà sí ilẹ̀ yín ni. N óo le yín jáde; ẹ óo sì ṣègbé. Ṣugbọn orílẹ̀-èdè tí ó bá ti ọrùn ara rẹ̀ bọ àjàgà ọba Babiloni, tí ó sì ń sìn ín, n óo fi sílẹ̀ lórí ilẹ̀ rẹ̀, kí ó lè máa ro ó, kí ó sì máa gbé ibẹ̀. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” Iṣẹ́ yìí kan náà ni mo jẹ́ fún Sedekaya ọba Juda. Mo ní, “Fi ọrùn rẹ sinu àjàgà ọba Babiloni, kí o sin òun ati àwọn eniyan rẹ̀, kí o lè wà láàyè. Kí ló dé tí ìwọ ati àwọn eniyan rẹ fẹ́ kú ikú idà, ikú ìyàn ati ikú àjàkálẹ̀ àrùn bí OLUWA ti wí pé yóo rí fún orílẹ̀-èdè tí ó bá kọ̀ tí kò bá sin ọba Babiloni? Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wolii tí wọn ń wí fun yín pé ẹ kò ní ṣe ẹrú ọba Babiloni, nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fun yín. OLUWA ní òun kò rán wọn níṣẹ́. Wọ́n kàn ń fi orúkọ òun sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ni, kí òun lè le yín jáde, kí ẹ sì ṣègbé, àtẹ̀yin àtàwọn wolii tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun yín.” Lẹ́yìn náà, mo bá àwọn alufaa ati gbogbo àwọn eniyan náà sọ̀rọ̀, mo ní, “OLUWA sọ pé ẹ kò gbọdọ̀ fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wolii yín tí wọn ń wí fun yín pé wọn kò ní pẹ́ kó àwọn ohun èlò ilé èmi OLUWA pada wá láti Babiloni. Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fun yín. Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ wọn. Ẹ sin ọba Babiloni, kí ẹ lè wà láàyè. Kí ló dé tí ìlú yìí yóo fi di ahoro? Bí wọn bá jẹ́ wolii nítòótọ́, bí ó bá jẹ́ pé èmi OLUWA ni mo fi ọ̀rọ̀ sí wọn lẹ́nu, ẹ ní kí wọn gbadura sí èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun, kí n má jẹ́ kí wọ́n kó àwọn ohun èlò tí ó kù ní ilé OLUWA ati ní ààfin ọba Juda ati ní Jerusalẹmu lọ sí Babiloni.” Àwọn ohun èlò kan ṣẹ́kù ninu ilé OLUWA, àwọn bíi: òpó ilé, ati agbada omi tí a fi idẹ ṣe, ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ati àwọn ohun èlò tí ó kù ninu ìlú yìí, tí Nebukadinesari, ọba Babiloni, kò kó lọ, nígbà tí ó kó Jehoiakini, ọba Juda, ọmọ Jehoiakimu, ati gbogbo àwọn ọlọ́lá Juda ati ti Jerusalẹmu lọ sí Babiloni. OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, “Gbogbo àwọn ohun èlò tí ó ṣẹ́kù ní ilé rẹ, ati ní ààfin ọba Juda, ati ní Jerusalẹmu, ni wọn óo kó lọ sí Babiloni, níbẹ̀ ni wọn yóo sì wà títí di ọjọ́ tí mo bá ranti wọn. N óo wá kó wọn pada wá sí ibí yìí nígbà náà.” Ní ọdún kan náà, ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekaya, ọba Juda, ní oṣù karun-un ọdún kẹrin, Hananaya wolii ọmọ Aṣuri, tí ó wá láti Gibeoni bá mi sọ̀rọ̀ ní ilé OLUWA lójú àwọn alufaa ati gbogbo àwọn eniyan pé, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní òun ti ṣẹ́ àjàgà ọba Babiloni. Kí ó tó pé ọdún meji, òun óo kó gbogbo ohun èlò tẹmpili òun pada, tí Nebukadinesari ọba Babiloni kó láti ibí yìí lọ sí Babiloni. Òun óo mú Jehoiakini ọba Juda, ọmọ Jehoiakimu, ati gbogbo àwọn tí a kó lẹ́rú láti Juda lọ sí Babiloni pada sí ibí yìí, nítorí òun óo ṣẹ́ àjàgà ọba Babiloni. Ó ní OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.” Jeremaya wolii bá dá Hananaya wolii lóhùn níṣojú àwọn alufaa ati gbogbo àwọn ará ìlú tí wọn dúró ní ilé OLUWA, ó ní, “Amin, kí OLUWA ṣe bẹ́ẹ̀. Kí OLUWA mú àsọtẹ́lẹ̀ tí o sọ ṣẹ, kí ó kó àwọn ohun èlò ilé rẹ̀ ati gbogbo àwọn eniyan tí a kó lẹ́rú lọ sí Babiloni pada sí ibí yìí. Ṣugbọn gbọ́ ohun tí n óo sọ fún ìwọ ati gbogbo àwọn eniyan wọnyi. Àwọn wolii tí wọ́n ti wà ṣáájú èmi pẹlu rẹ ní ìgbà àtijọ́ sọ àsọtẹ́lẹ̀ ogun, ìyàn, ati àjàkálẹ̀ àrùn nípa ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ati nípa àwọn ìjọba ńláńlá. Wolii tí ó bá fẹ́ sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé alaafia yóo wà, nígbà tí ọ̀rọ̀ wolii náà bá ṣẹ ni a óo mọ̀ pé OLUWA ni ó rán an níṣẹ́ nítòótọ́.” Hananaya wolii bá bọ́ àjàgà kúrò lọ́rùn Jeremaya, ó sì ṣẹ́ ẹ. Hananaya bá sọ níṣojú gbogbo eniyan pé OLUWA ní bẹ́ẹ̀ ni òun óo ṣẹ́ àjàgà Nebukadinesari ọba Babiloni kúrò lọ́rùn gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè kí ọdún meji tó pé. Wolii Jeremaya bá bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ. Lẹ́yìn tí Hananaya wolii bọ́ àjàgà kúrò lọ́rùn Jeremaya, tí ó sì ṣẹ́ ẹ, OLUWA sọ fún Jeremaya pé, “Lọ sọ fún Hananaya pé OLUWA ní àjàgà igi ni ó ṣẹ́, ṣugbọn àjàgà irin ni òun óo fi rọ́pò rẹ̀. OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní òun ti fi àjàgà irin sí ọrùn gbogbo orílẹ̀-èdè wọnyi kí wọn lè di ẹrú Nebukadinesari ọba Babiloni, kí wọn sì máa sìn ín, nítorí òun ti fi àwọn ẹranko inú igbó pàápàá fún un.” Jeremaya wolii bá sọ fún Hananaya pé, “Tẹ́tí sílẹ̀, Hananaya, OLUWA kò rán ọ níṣẹ́, o sì ń jẹ́ kí àwọn eniyan wọnyi gbẹ́kẹ̀lé irọ́. Nítorí náà, OLUWA ní: òun óo mú ọ kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Ní ọdún yìí gan-an ni o óo sì kú, nítorí pé o ti sọ ọ̀rọ̀ ọ̀tẹ̀ sí OLUWA.” Ní ọdún náà gan-an ní oṣù keje, ni Hananaya wolii kú. Jeremaya wolii kọ ìwé kan ranṣẹ láti Jerusalẹmu, ó kọ ọ́ sí àwọn àgbààgbà láàrin àwọn tí a kó ní ìgbèkùn; ati sí àwọn alufaa ati àwọn wolii, ati gbogbo àwọn eniyan tí Nebukadinesari kó ní ìgbèkùn lọ sí Babiloni, láti Jerusalẹmu. Ṣáájú àkókò yìí, ọba Jehoiakini ati ìyá ọba ti kúrò ní Jerusalẹmu, pẹlu àwọn ìwẹ̀fà ati àwọn ìjòyè Juda ati ti Jerusalẹmu, ati àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ ati àwọn oníṣẹ́-ọnà. Ó fi ìwé náà rán Elasa, ọmọ Ṣafani ati Gemaraya, ọmọ Hilikaya: àwọn tí Sedekaya, ọba Juda, rán lọ sọ́dọ̀ Nebukadinesari, ọba Babiloni. Ó ní, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní kí n sọ fún gbogbo àwọn tí a ti kó ní ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babiloni pé, ‘Ẹ máa kọ́ ilé kí ẹ sì máa gbé inú wọn, ẹ máa dá oko kí ẹ sì máa jẹ èso wọn. Ẹ máa gbé iyawo kí ẹ bímọ lọkunrin ati lobinrin. Ẹ máa fẹ́ iyawo fún àwọn ọmọ yín, kí ẹ sì fi àwọn ọmọ yín fún ọkọ, kí wọn lè máa bímọ lọkunrin ati lobinrin. Ẹ máa pọ̀ sí i, ẹ má sì dínkù. Ẹ máa wá alaafia ìlú tí mo ko yín lọ, ẹ máa gbadura sí OLUWA fún un, nítorí pé ninu alaafia rẹ̀ ni ẹ̀yin náà yóo ti ní alaafia. Nítorí èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli sọ pé kí ẹ má jẹ́ kí àwọn wolii ati àwọn tí wọn ń woṣẹ́ láàrin yín tàn yín jẹ, kí ẹ má sì fetí sí àlá tí wọn ń lá; nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fun yín ní orúkọ mi, n kò rán wọn níṣẹ́.’ “Nígbà tí aadọrin ọdún Babiloni bá pé, n óo mójú tó ọ̀rọ̀ yín, n óo mú ìlérí mi ṣẹ fun yín, n óo sì ko yín pada sí ibí yìí. Nítorí pé mo mọ èrò tí mò ń gbà si yín, èrò alaafia ni, kì í ṣe èrò ibi. N óo mú kí ọjọ́ ọ̀la dára fun yín, n óo sì fun yín ní ìrètí. Ẹ óo ké pè mí, ẹ óo gbadura sí mi, n óo sì gbọ́ adura yín. Ẹ óo wá mi, ẹ óo sì rí mi, bí ẹ bá fi tọkàntọkàn wá mi. Ẹ óo rí mi, n óo dá ire yín pada, n óo ko yín jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè ati láti gbogbo ibi tí mo ti le yín lọ; n óo sì ko yín pada sí ibi tí mo ti le yín kúrò lọ sí ìgbèkùn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “Nítorí ẹ wí pé, ‘OLUWA ti gbé àwọn wolii dìde fun wa ní Babiloni.’ Nípa ti ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, ati gbogbo àwọn tí ń gbé ìlú yìí, àní àwọn ará yín tí wọn kò ba yín lọ sí ìgbèkùn, OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, ‘N óo rán ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn sí wọn, n óo sì ṣe wọ́n bí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó bàjẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè jẹ ẹ́.’ Ó ní, ‘N óo fi ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn bá wọn jà, òun óo sì sọ wọ́n di àríbẹ̀rù fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé. Wọn yóo di ẹni ègún, àríbẹ̀rù, àrípòṣé ati ẹni ẹ̀sín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí mo lé wọn lọ. Nítorí pé wọn kò fetí sí ọ̀rọ̀ tí mo rán àwọn iranṣẹ mi, àwọn wolii, láti sọ fún wọn nígbà gbogbo. Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA sọ, gbogbo ẹ̀yin tí OLUWA kó ní ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babiloni.’ “Ohun tí OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli sọ nípa Ahabu ọmọ Jehoiakini, ati Sedekaya ọmọ Maaseaya, tí wọn ń forúkọ mi sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fun yín ni pé: òun óo fi wọ́n lé Nebukadinesari ọba Babiloni lọ́wọ́, yóo sì pa wọ́n lójú yín. Gbogbo àwọn ará Juda tí wọ́n wà ní ìgbèkùn ní Babiloni yóo máa fi ọ̀rọ̀ wọn ṣépè fún eniyan pé: ‘OLUWA yóo ṣe ọ́ bíi Sedekaya ati Ahabu tí ọba Babiloni sun níná,’ nítorí pé wọ́n ti hùwà òmùgọ̀ ní Israẹli, wọ́n bá aya àwọn aládùúgbò wọn ṣe àgbèrè, wọ́n fi orúkọ òun sọ ọ̀rọ̀ èké tí òun kò fún wọn láṣẹ láti sọ. OLUWA ní òun nìkan ni òun mọ ohun tí wọ́n ṣe; òun sì ni ẹlẹ́rìí.” OLUWA ní kí n sọ fún Ṣemaaya tí ń gbé Nehelamu pé, “Èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, nítorí ìwé tí o fi orúkọ ara rẹ kọ sí gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu, ati sí Sefanaya alufaa, ọmọ Maaseaya, ati sí gbogbo àwọn alufaa, pé: “Èmi OLUWA ti fi ìwọ Sefanaya jẹ alufaa dípò Jehoiada tí ó jẹ́ alufaa tẹ́lẹ̀ rí, ati pé mo ní kí o máa ṣe alabojuto gbogbo àwọn wèrè tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ilé èmi OLUWA, kí o sì máa kan ààbà mọ́ wọn ní ẹsẹ̀, kí o máa fi okùn sí wọn lọ́rùn. Kí ló dé tí o kò bá Jeremaya ará Anatoti tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun yín wí. Nítorí ó ti ranṣẹ sí wa ní Babiloni pé a á pẹ́ níbí, nítorí náà kí á kọ́lé, kí á máa gbé inú rẹ̀, kí á dá oko, kí á sì máa jẹ èso rẹ̀.” Sefanaya Alufaa ka ìwé náà sí etí Jeremaya wolii. OLUWA bá sọ fún Jeremaya pé, “Ranṣẹ sí gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèkùn wí pé ohun tí OLUWA wí nípa Ṣemaaya ará Nehelamu ni pé: nítorí pé Ṣemaaya sọ àsọtẹ́lẹ̀ tí òun kò rán an, ó sì mú kí ẹ gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ èké, òun OLUWA óo fìyà jẹ Ṣemaaya ará Nehelamu náà ati ìran rẹ̀; kò ní sí ẹnikẹ́ni tí yóo wà láàyè láàrin àwọn eniyan rẹ̀ láti fojú rí nǹkan rere tí n óo ṣe fún àwọn eniyan mi, nítorí ó ti sọ̀rọ̀ ọ̀tẹ̀ sí OLUWA.” OLUWA Ọlọrun Israẹli bá Jeremaya sọ̀rọ̀: Ó ní, “Kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fún ọ sinu ìwé, nítorí pé àkókò ń bọ̀ tí n óo dá ire àwọn eniyan mi, Israẹli ati Juda pada. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo mú wọn pada wá sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá wọn, yóo sì di ohun ìní wọn.” Ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ nípa Israẹli ati Juda nìyí: “A ti gbọ́ igbe ìdágìrì ati ti ẹ̀rù, kò sì sí alaafia. Ẹ bèèrè, kí ẹ sì ṣe ìwádìí; ǹjẹ́ ọkunrin lè lóyún kí ó sì bímọ? Kí ló wá dé tí mo rí gbogbo ọkunrin, tí wọn ń dáwọ́ tẹ ìbàdí bí obinrin tí ń rọbí? Kí ló dé tí gbogbo yín fajúro? Ọjọ́ ńlá lọjọ́ náà yóo jẹ́, kò sí ọjọ́ tí yóo dàbí rẹ̀, àkókò ìpọ́njú ni yóo jẹ́ fún ilé Jakọbu; ṣugbọn wọn yóo bọ́ ninu rẹ̀.” OLUWA ní, “Nígbà tí ó bá yá, n óo já àjàgà kúrò lọ́rùn wọn. N óo já ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi so wọ́n, wọn kò sì ní ṣe iranṣẹ fún àjèjì mọ́. Ṣugbọn wọn yóo máa sin Ọlọrun wọn, ati ti Dafidi, ọba wọn, tí n óo gbé dìde fún wọn. “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin eniyan Jakọbu, iranṣẹ mi, ẹ má sì jẹ́ kí àyà fò yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo ti òkèèrè wá gbà yín là, N óo gba àwọn ọmọ yín tí wọ́n wà ní ìgbèkùn là pẹlu. Àwọn ọmọ Jakọbu yóo pada ní ìfọ̀kànbalẹ̀ ati ìrọ̀rùn, ẹnikẹ́ni kò sì ní dẹ́rù bà wọ́n mọ́. Nítorí pé mo wà pẹlu yín, n óo gbà yín là. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n óo pa gbogbo orílẹ̀-èdè run, gbogbo orílẹ̀-èdè tí mo fọn yín ká sí ni n óo parun patapata, ṣugbọn n kò ní pa ẹ̀yin run. N óo jẹ yín níyà, ṣugbọn n kò ní fi ìyà tí kò tọ́ jẹ yín. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “Egbò yín kò lè san mọ́, ọgbẹ́ yín sì jinlẹ̀. Kò sí ẹni tí yóo gba ẹjọ́ yín rò, kò ní sí òògùn fún ọgbẹ́ yín, kò ní sí ìwòsàn fun yín. Gbogbo àwọn olólùfẹ́ yín ti gbàgbé yín; wọn kò bìkítà nípa yín mọ́, nítorí mo ti nà yín bí ọ̀tá mi, mo sì fi ìyà jẹ yín bí ọ̀tá tí kò láàánú, nítorí àṣìṣe yín pọ̀, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín pọ̀ rékọjá ààlà. Kí ló dé tí ẹ̀ ń sunkún, nítorí ìnira yín tí kò lóògùn? Nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ yín pọ̀ rékọjá ààlà ni mo ṣe jẹ́ kí àwọn nǹkan wọnyi dé ba yín. Ṣugbọn, gbogbo àwọn tí wọ́n bá jẹ yín run, ni a óo pada jẹ run. Gbogbo àwọn ọ̀tá yín patapata, ni yóo lọ sí ìgbèkùn. Gbogbo àwọn tí wọ́n fogun kó yín ni ogun yóo kó. N óo fi ẹrù àwọn tí wọn ń jà yín lólè fún àwọn akónilẹ́rù. N óo fun yín ní ìlera, n óo sì wo àwọn ọgbẹ́ yín sàn, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Nítorí wọ́n ti pè yín ní ‘Ẹni ìtanù, Sioni tí ẹnikẹ́ni kò bìkítà fún.’ ” OLUWA ní, “Mo ṣetán láti dá ire ilé Jakọbu pada, n óo fi ojurere wo ibùgbé rẹ̀. A óo tún ìlú náà kọ́ sórí òkítì rẹ̀, a óo sì tún kọ́ ààfin rẹ̀ sí ààyè rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Orin ọpẹ́ yóo máa ti ibẹ̀ jáde wá, a óo sì máa gbọ́ ohùn àwọn tí ń ṣe àríyá pẹlu. N óo bukun wọn, wọn óo di pupọ, n óo sọ wọ́n di ẹni iyì, wọn kò sì ní jẹ́ eniyan yẹpẹrẹ. Àwọn ọmọ wọn yóo rí bí wọn ti rí ní àtijọ́, àwọn ìjọ wọn yóo fi ìdí múlẹ̀ níwájú mi. N óo sì fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí wọn ń ni wọ́n lára. Ọ̀kan ninu wọn ni yóo jọba lórí wọn, ààrin wọn ni a óo sì ti yan olórí wọn; n óo fà á mọ́ra, yóo sì súnmọ́ mi, nítorí pé kò sí ẹni tí ó lè fúnra rẹ̀ súnmọ́ mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Ẹ óo jẹ́ eniyan mi, n óo sì jẹ́ Ọlọrun yín.” Ẹ wo ìjì OLUWA! Ibinu rẹ̀ ń bọ̀ bí ìjì líle. Ó ń bọ̀ sórí àwọn oníṣẹ́ ibi. Ibinu gbígbóná OLUWA kò ní yipada, títí yóo fi mú èrò ọkàn rẹ̀ ṣẹ. Òye nǹkan wọnyi yóo ye yín ní ọjọ́ ìkẹyìn. OLUWA ní, “Àkókò ń bọ̀ tí n óo jẹ́ Ọlọrun gbogbo ìdílé Israẹli, tí àwọn náà yóo sì jẹ́ eniyan mi. Àwọn tí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ idà, rí àánú OLUWA ninu aṣálẹ̀; nígbà tí Israẹli ń wá ìsinmi, OLUWA yọ sí wọn láti òkèèrè. Ìfẹ́ àìlópin ni mo ní sí ọ, nítorí náà n kò ní yé máa fi òtítọ́ bá ọ lò. N óo tún yín gbé dìde, ẹ óo sì di ọ̀tun, ẹ̀yin ọmọ Israẹli. Ẹ óo tún fi aro lu ìlù ayọ̀, ẹ óo sì jó ijó ìdùnnú. Ẹ óo tún ṣe ọgbà àjàrà sórí òkè Samaria; àwọn tí wọ́n gbin àjàrà ni yóo sì gbádùn èso orí rẹ̀. Nítorí pé ọjọ́ kan ń bọ̀, tí àwọn aṣọ́nà yóo pè yín láti orí òkè Efuraimu pé, ‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí á lọ sí òkè Sioni, sí ọ̀dọ̀ OLUWA Ọlọrun wa.’ ” OLUWA ní, “Ẹ kọ orin sókè pẹlu ìdùnnú fún Jakọbu, kí ẹ sì hó fún olórí àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ kéde, ẹ kọ orin ìyìn, kí ẹ sì wí pé, ‘OLUWA ti gba àwọn eniyan rẹ̀ là àní, àwọn eniyan Israẹli yòókù.’ Ẹ wò ó! N óo kó wọn wá láti ilẹ̀ àríwá, n óo kó wọn jọ láti òpin ayé. Àwọn afọ́jú ati arọ yóo wà láàrin wọn, ati aboyún ati àwọn tí wọn ń rọbí lọ́wọ́. Ogunlọ́gọ̀ eniyan ni àwọn tí yóo pada wá síbí. Tẹkúntẹkún ni wọn yóo wá, tàánútàánú ni n óo sì fi darí wọn pada. N óo mú kí wọn rìn ní etí odò tí ń ṣàn, lójú ọ̀nà tààrà, níbi tí wọn kò ti ní fẹsẹ̀ kọ; nítorí pé baba ni mo jẹ́ fún Israẹli, àkọ́bí mi sì ni Efuraimu.” OLUWA ní, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ èmi OLUWA, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, kí ẹ sì kéde rẹ̀ ní èbúté lókèèrè réré; ẹ sọ pé, ‘Ẹni tí ó fọ́n Israẹli ká ni yóo kó wọn jọ, yóo sì máa tọ́jú wọn, bí olùṣọ́-aguntan tíí tọ́jú agbo aguntan rẹ̀.’ Nítorí OLUWA yóo ra ilé Jakọbu pada, yóo rà wọ́n pada lọ́wọ́ ẹni tí ó lágbára jù wọ́n lọ. Wọn yóo wá kọrin lórí òkè Sioni, wọn óo sì yọ̀ lórí nǹkan ọ̀pọ̀ oore tí OLUWA yóo ṣe fún wọn: Wọ́n óo yọ̀ nítorí oore ọkà ati waini ati òróró, ati aguntan ati ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù; ayé wọn óo dàbí ọgbà tí à ń bomi rin, wọn kò ní dààmú mọ́. Àwọn ọdọmọbinrin óo máa jó ijó ayọ̀ nígbà náà, àwọn ọdọmọkunrin ati àwọn àgbààgbà, yóo sì máa ṣe àríyá. N óo sọ ọ̀fọ̀ wọn di ayọ̀, n óo tù wọ́n ninu, n óo sì fún wọn ní ayọ̀ dípò ìbànújẹ́ wọn. N óo fún àwọn alufaa ní ọpọlọpọ oúnjẹ, n óo sì fi oore mi tẹ́ àwọn eniyan mi lọ́rùn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA ní, “A gbọ́ ohùn kan ní Rama, ariwo ẹkún ẹ̀dùn ati arò ni. Rakẹli ń sọkún àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n ṣìpẹ̀ fún un títí, kò gbà, nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ tí kò sí mọ́. Má sọkún mọ́, nu ojú rẹ nù, nítorí o óo jẹ èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Àwọn ọmọ rẹ yóo pada wá láti ilẹ̀ ọ̀tá wọn. Ìrètí ń bẹ fún ọ lẹ́yìn ọ̀la, àwọn ọmọ rẹ yóo pada sí orílẹ̀-èdè wọn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “Mo gbọ́ bí Efuraimu tí ń kẹ́dùn, ó ní: ‘O ti bá mi wí, ìbáwí sì dùn mí, bí ọmọ mààlúù tí a kò kọ́. Mú mi pada, kí n lè pada sí ààyè mi, nítorí pé ìwọ ni OLUWA, Ọlọrun mi. Nítorí pé lẹ́yìn tí mo ṣáko lọ, mo ronupiwada; lẹ́yìn tí o kọ́ mi lọ́gbọ́n, ń ṣe ni mo káwọ́ lérí. Ojú tì mí, ìdààmú sì bá mi, nítorí ìtìjú ohun tí mo ṣe nígbà èwe mi dé bá mi.’ “Ṣé ọmọ mi ọ̀wọ́n ni Efuraimu ni? Ṣé ọmọ mi àtàtà ni? Nítorí bí mo tí ń sọ̀rọ̀ ibinu sí i tó, sibẹ mò ń ranti rẹ̀, nítorí náà ọkàn rẹ̀ ń fà mí; dájúdájú n óo ṣàánú rẹ̀. Ẹ ri òpó mọ́lẹ̀ lọ fún ara yín, ẹ sàmì sí àwọn ojú ọ̀nà. Ẹ wo òpópónà dáradára, ẹ fiyèsí ọ̀nà tí ẹ gbà lọ. Ẹ yipada, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ pada sí àwọn ìlú yín wọnyi. Ìgbà wo ni ẹ óo ṣe iyèméjì dà, ẹ̀yin alainigbagbọ wọnyi? Nítorí OLUWA ti dá ohun titun sórí ilẹ̀ ayé, bíi kí obinrin máa dáàbò bo ọkunrin.” OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, “Lẹ́ẹ̀kan sí i, wọn yóo tún máa lo gbolohun yìí ní ilẹ̀ Juda ati ní àwọn ìlú rẹ̀, nígbà tí mo bá dá ire wọn pada, wọn óo máa wí pé, ‘OLUWA yóo bukun ọ, ìwọ òkè mímọ́ Jerusalẹmu, ibùgbé olódodo.’ Àwọn eniyan yóo máa gbé àwọn ìlú Juda ati àwọn agbègbè rẹ̀ pẹlu àwọn àgbẹ̀ ati àwọn darandaran. Nítorí pé n óo fún àwọn tí àárẹ̀ mú ní agbára; n óo sì tu gbogbo ọkàn tí ń kérora lára.” Lẹ́sẹ̀ kan náà mo tají, mo wò yíká, oorun tí mo sùn sì dùn mọ́ mi. OLUWA ní, “Ọjọ́ ń bọ̀ tí n óo kó àtènìyàn, àtẹranko kún ilẹ̀ Israẹli ati ilẹ̀ Juda. Nígbà tí àkókò bá tó, gẹ́gẹ́ bí mo tí ń ṣọ́ wọn tí mo fi fà wọ́n tu, tí mo wó wọn lulẹ̀, tí mo bì wọ́n wó, tí mo pa wọ́n run, tí mo sì mú kí ibi ó bá wọn; bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣọ́ wọn tí n óo fi kọ́ àwọn ìlú wọn tí n óo sì fìdí wọn múlẹ̀. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Tó bá dìgbà náà, àwọn eniyan kò ní máa wí mọ́ pé, ‘Àwọn baba ni wọ́n jẹ èso àjàrà kíkan, àwọn ọmọ wọn ni eyín kan.’ Kàkà bẹ́ẹ̀ ẹni tí ó bá jẹ èso àjàrà kíkan, òun ni eyín yóo kan. Olukuluku ni yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀. “Ọjọ́ ń bọ̀, tí ń óo bá ilé Israẹli ati ilé Juda dá majẹmu titun. Kì í ṣe irú majẹmu tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá, ní ìgbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́ jáde ní ilẹ̀ Ijipti, àní majẹmu mi tí wọn dà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi ni ọkọ wọn. Ṣugbọn majẹmu tí n óo bá ilé Israẹli dá nígbà tó bá yá nìyí: N óo fi òfin mi sí inú wọn, n óo sì kọ wọ́n sí ọkàn wọn. N óo máa jẹ́ Ọlọrun wọn, wọn yóo sì máa jẹ́ eniyan mi. Ẹnikẹ́ni kò ní máa kọ́ aládùúgbò rẹ̀ tabi arakunrin rẹ̀ bí a ti í mọ èmi OLUWA mọ́, gbogbo wọn ni wọn yóo mọ̀ mí ati àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan pataki pataki. N óo dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, n kò sì ní ranti àìdára wọn mọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA ni ó dá oòrùn, láti máa ràn ní ọ̀sán, tí ó fún òṣùpá ati ìràwọ̀ láṣẹ, láti tan ìmọ́lẹ̀ lálẹ́, tí ó rú omi òkun sókè, tí ìgbì rẹ̀ ń hó yaya, òun ni orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun. Òun ló sọ pé, àfi bí àwọn àṣẹ wọnyi bá yipada níwájú òun, ni àwọn ọmọ Israẹli kò fi ní máa jẹ́ orílẹ̀-èdè títí lae. Àfi bí eniyan bá lè wọn ojú ọ̀run, tí ó sì lè wádìí ìpìlẹ̀ ayé, ni òun lè ké àwọn ọmọ Israẹli kúrò, nítorí gbogbo ohun tí wọ́n ṣe. OLUWA ni, “Ẹ wò ó! Àkókò ń bọ̀ tí a óo tún Jerusalẹmu kọ́ fún mi láti ilé ìṣọ́ Hananeli títí dé Bodè Igun. A óo ta okùn ìwọ̀n odi ìlú títí dé òkè Garebu, ati títí dé Goa pẹlu. Gbogbo àfonífojì tí wọn ń da òkú ati eérú sí, ati gbogbo pápá títí dé odò Kidironi, dé ìkangun Bodè Ẹṣin, ní ìhà ìlà oòrùn, ni yóo jẹ́ ibi mímọ́ fún OLUWA. Wọn kò ní fọ́ ọ mọ́, ẹnìkan kò sì ní wó o lulẹ̀ títí laelae.” OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀ ní ọdún kẹwaa tí Sedekaya jọba ní Juda, tí ó jẹ́ ọdún kejidinlogun tí Nebukadinesari jọba. Àwọn ọmọ ogun Babiloni dó ti Jerusalẹmu ní àkókò yìí, Jeremaya wolii sì wà ní ẹ̀wọ̀n tí wọ́n sọ ọ́ sí, ní àgbàlá ààfin ọba Juda. Sedekaya ọba Juda ni ó sọ Jeremaya sẹ́wọ̀n, ó ní, kí ló dé tí Jeremaya fi sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé OLUWA ní òun óo fi Jerusalẹmu lé ọba Babiloni lọ́wọ́, yóo sì gbà á; ati pé Sedekaya ọba Juda kò ní bọ́ lọ́wọ́ àwọn ará Kalidea. Ó ní Jeremaya sọ pé dájúdájú, OLUWA óo fi òun Sedekaya lé ọba Babiloni lọ́wọ́, àwọn yóo rí ara àwọn lojukooju, àwọn yóo sì bá ara àwọn sọ̀rọ̀. Yóo mú òun Sedekaya lọ sí Babiloni, ibẹ̀ ni òun óo sì wà títí OLUWA yóo fi ṣe ẹ̀tọ́ fún òun. Ó ní bí àwọn tilẹ̀ bá àwọn ará Kalidea jagun, àwọn kò ní borí. Jeremaya ní, “OLUWA sọ fún mi pé, ‘Hanameli ọmọ Ṣalumu, arakunrin baba rẹ, yóo wá bá ọ pé kí o ra oko òun tí ó wà ní Anatoti, nítorí pé ìwọ ni ó tọ́ sí láti rà á pada.’ Lẹ́yìn náà Hanameli ọmọ arakunrin baba mi tọ̀ mí wá sí àgbàlá àwọn olùṣọ́ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ, ó sì wí fún mi pé, ‘Jọ̀wọ́ ra oko mi tí ó wà ní Anatoti ní ilẹ̀ Bẹnjamini, nítorí pé ìwọ ni ó tọ́ sí láti rà á pada; rà á fún ara rẹ.’ “Nígbà náà ni mo wá mọ̀ pé àṣẹ OLUWA ni. Mo bá ra oko náà lọ́wọ́ Hanameli ọmọ arakunrin baba mi, mo sì wọn fadaka ṣekeli mẹtadinlogun fún un. Mo kọ ọ́ sinu ìwé, mo fi òǹtẹ̀ tẹ̀ ẹ́, mo pe àwọn eniyan láti ṣe ẹlẹ́rìí; mo sì fi òṣùnwọ̀n wọn fadaka náà. Mo mú ìwé ilẹ̀ náà tí a ti fi òǹtẹ̀ tẹ̀ ati ẹ̀dà rẹ̀, mo sì fún Baruku ọmọ Neraya ọmọ Mahiseaya ní èyí tí a fi òǹtẹ̀ tẹ̀, níṣojú Hanameli, ọmọ arakunrin baba mi ati níṣojú àwọn ẹlẹ́rìí tí wọn fọwọ́ sí ìwé ilẹ̀ náà, ati níṣojú gbogbo àwọn ará Juda tí wọn jókòó ní àgbàlá àwọn olùṣọ́ náà. Mo pàṣẹ fún Baruku níṣojú wọn pé, ‘OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní kí o mú ìwé ilẹ̀ yìí, ati èyí tí a fi òǹtẹ̀ tẹ̀ tí a sì ká, ati ẹ̀dà rẹ̀, kí o fi wọ́n sinu ìkòkò amọ̀ kí wọ́n lè wà níbẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́. Nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli sọ pé: wọn yóo tún máa ra ilẹ̀ ati oko ati ọgbà àjàrà ní ilẹ̀ yìí.’ “Lẹ́yìn tí mo ti fi ìwé ilẹ̀ náà lé Baruku ọmọ Neraya lọ́wọ́, mo gbadura sí OLUWA, mo ní: ‘OLUWA, Ọlọrun! Ìwọ tí o dá ọ̀run ati ayé pẹlu agbára ńlá ati ipá rẹ! Kò sí ohun tí ó ṣòro fún ọ, ìwọ tí ò ń fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn fún ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, ṣugbọn tí ò ń gba ẹ̀san àwọn baba lára àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn ikú wọn, ìwọ Ọlọrun alágbára ńlá tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun, ìwọ Olùdámọ̀ràn ńlá, tí ó lágbára ní ìṣe; ìwọ tí ojú rẹ ń rí sí gbogbo ọ̀nà àwọn ọmọ eniyan, tí o sì ń san ẹ̀san fún olukuluku gẹ́gẹ́ bí ìwà ati iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀; ìwọ tí o ṣe iṣẹ́ abàmì, ati iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Ijipti, o sì tún ń ṣe iṣẹ́ náà títí di òní ní Israẹli ati láàrin gbogbo eniyan; o sì ti fìdí orúkọ rẹ múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí lónìí. Ìwọ ni o kó àwọn ọmọ Israẹli, àwọn eniyan rẹ, jáde láti ilẹ̀ Ijipti pẹlu iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu, pẹlu ọwọ́ agbára, ipá ati ìbẹ̀rù ńlá. O sì fún wọn ní ilẹ̀ yìí, ilẹ̀ tí o búra fún àwọn baba ńlá wọn pé o óo fún wọn, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin. Wọ́n dé ilẹ̀ náà, wọ́n sì gbà á; ṣugbọn wọn kò gbọ́rọ̀ sí ọ lẹ́nu, wọn kò sì pa òfin rẹ mọ́. Wọn kò ṣe ọ̀kan kan ninu gbogbo ohun tí o pàṣẹ fún wọn láti máa ṣe; nítorí náà ni o ṣe mú kí gbogbo ibi tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn bá wọn! “ ‘Wo bí àwọn ọ̀tá ti mọ òkítì sí ara odi wa láti gba ìlú wa. Nítorí ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn, a óo fi ìlú yìí lé àwọn ará Kalidea tí wọn gbógun tì í lọ́wọ́. Ohun tí o wí ṣẹ, o sì ti rí i. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti fi ìlú yìí lé àwọn ará Kalidea lọ́wọ́, sibẹsibẹ, ìwọ OLUWA Ọlọrun ni o sọ fún mi pé kí n ra ilẹ̀, kí n sì ní àwọn ẹlẹ́rìí.’ ” OLUWA sọ fún Jeremaya pé, “Wò ó! Èmi ni OLUWA, Ọlọrun gbogbo eniyan, ǹjẹ́ nǹkankan wà tí ó ṣòro fún mi láti ṣe? Nítorí náà èmi OLUWA ni mo sọ pé, n óo fi ìlú yìí lé àwọn ará Kalidea ati Nebukadinesari, ọba Babiloni lọ́wọ́, yóo sì gbà á. Àwọn ará Kalidea tí wọn gbógun ti ìlú yìí, yóo wọ inú rẹ̀, wọn yóo sì dáná sun ún pẹlu àwọn ilẹ̀ tí wọ́n tí ń sun turari sí oriṣa Baali lórí wọn, tí wọ́n sì tí ń rú ẹbọ ohun mímu sí àwọn oriṣa tí wọn ń mú mi bínú. Nítorí láti ìgbà èwe àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn eniyan Juda ni wọ́n tí ń ṣe kìkì nǹkan tí ó burú lójú mi, kìkì nǹkan tí yóo bí mi ninu ni àwọn ọmọ Israẹli náà sì ń ṣe. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Láti ọjọ́ tí wọn ti tẹ ìlú yìí dó títí di òní, ni àwọn ará ilẹ̀ yìí tí ń mú mi bínú, tí wọn sì ń mú kí inú mi ó máa ru, kí n lè pa wọ́n rẹ́ kúrò níwájú mi, nítorí gbogbo ibi tí àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn ará ilẹ̀ Juda ṣe láti mú mi bínú, àtàwọn ọba wọn, àtàwọn ìjòyè wọn, àtàwọn alufaa wọn, àtàwọn wolii wọn; àtàwọn ará Juda àtàwọn tí ń gbé Jerusalẹmu. Wọ́n ti yíjú kúrò lọ́dọ̀ mi, wọ́n sì kẹ̀yìn sí mi. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti kọ́ wọn ni àkọ́túnkọ́, wọn kò gba ẹ̀kọ́. Wọ́n gbé àwọn ère wọn, tí ó jẹ́ ohun ìríra fun mi sinu ilé tí à ń fi orúkọ mi pè, kí wọ́n lè sọ ọ́ di ibi àìmọ́. Wọ́n kọ́ ojúbọ oriṣa tí ó wà ní àfonífojì ọmọ Hinomu láti máa fi àwọn ọmọ wọn, lọkunrin ati lobinrin rú ẹbọ sí oriṣa Moleki, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò pa á láṣẹ fún wọn, tí kò sì wá sí mi lọ́kàn pé wọ́n lè ṣe irú ohun ìríra bẹ́ẹ̀, láti mú Juda dẹ́ṣẹ̀.” Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun Israẹli sọ fún mi pé, “Ìlú tí àwọn eniyan ń sọ pé ọwọ́ ọba Babiloni ti tẹ̀, nítorí ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn, n óo kó àwọn eniyan ibẹ̀ jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè tí mo ti fi ibinu, ìrúnú, ati ìkanra lé wọn lọ; n óo kó wọn pada sí ibí yìí, n óo sì mú kí wọn máa gbé ní àìléwu. Wọn yóo máa jẹ́ eniyan mi, Èmi náà óo sì máa jẹ́ Ọlọrun wọn. N óo fún wọn ní ọkàn ati ẹ̀mí kan, kí wọn lè máa bẹ̀rù mi nígbà gbogbo, kí ó lè dára fún àwọn ati àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn wọn. N óo bá wọn dá majẹmu ayérayé, pé n kò ní dẹ́kun ati máa ṣe wọ́n lóore. N óo fi ẹ̀rù mi sí wọn lọ́kàn, kí wọn má baà yapa kúrò lọ́dọ̀ mi mọ́. Yóo máa jẹ́ ohun ayọ̀ fún mi láti ṣe wọ́n lóore, n óo fi tẹ̀mítẹ̀mí ati tọkàntọkàn fi ìdí wọn múlẹ̀ ninu jíjẹ́ olóòótọ́ ní ilẹ̀ yìí. “Bí mo ṣe mú gbogbo ibi ńlá yìí bá àwọn eniyan wọnyi, bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe mú kí gbogbo ohun rere tí mo ti ṣe ìlérí fún wọn dé bá wọn. Wọn yóo ra oko ní ilẹ̀ yìí, ilẹ̀ tí ẹ̀ ń sọ pé ó ti di ahoro, tí kò sí eniyan tabi ẹranko ninu rẹ̀, tí ẹ̀ ń sọ pé a ti fi lé àwọn ará Kalidea lọ́wọ́. Wọn yóo máa fi owó ra oko, wọn yóo máa ṣe ìwé ilẹ̀, wọn yóo máa fi òǹtẹ̀ tẹ̀ ẹ́; wọn yóo máa fi èdìdì dì í, àwọn ẹlẹ́rìí yóo sì máa fi ọwọ́ sí i, bẹ́ẹ̀ ni yóo máa rí ní ilẹ̀ Bẹnjamini. Nígbà tí mo bá dá ire wọn pada, ati ní àwọn agbègbè Jerusalẹmu, ní àwọn ìlú Juda, ati àwọn ìlú agbègbè olókè, ní àwọn ìlú pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣefela, ati àwọn ìlú ilẹ̀ Nẹgẹbu. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀ lẹẹkeji, nígbà tí ó ṣì wà ní ẹ̀wọ̀n, ní àgbàlá àwọn tí ń ṣọ́ ààfin. OLUWA tí ó dá ayé, tí ó sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA, ni ó sọ pé: “Ẹ ké pè mí, n óo sì da yín lóhùn; n óo sọ nǹkan ìjìnlẹ̀ ati ìyanu ńlá, tí ẹ kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ fun yín.” OLUWA, Ọlọrun Israẹli sọ nípa àwọn ilé tí wọ́n wà ní ìlú yìí, ati ilé ọba Juda, àwọn tí wọn dótì wá, tí wọn ń gbógun tì wá yóo wó wọn lulẹ̀ Ó ní, “Àwọn ará Kalidea ń gbógun bọ̀, wọn yóo da òkú àwọn eniyan tí n óo fi ibinu ati ìrúnú pa kún àwọn ilé tí ó wà ní ìlú yìí, nítorí mo ti fi ara pamọ́ fún ìlú yìí nítorí gbogbo ìwà burúkú wọn. N óo mú ìlera ati ìwòsàn wá bá wọn; n óo wò wọ́n sàn, n óo sì fún wọn ní ọpọlọpọ ibukun ati ìfọ̀kànbalẹ̀. N óo dá ire Juda ati ti Israẹli pada, n óo sì tún wọn kọ́, wọn yóo dàbí wọ́n ti rí lákọ̀ọ́kọ́. N óo wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò ninu gbogbo ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá sí mi, n óo dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ati oríkunkun tí wọ́n ṣe sí mi jì wọ́n. Orúkọ ìlú yìí yóo sì jẹ́ orúkọ ayọ̀ fún mi, yóo jẹ́ ohun ìyìn ati ògo níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè ayé tí yóo gbọ́ nípa nǹkan rere tí n óo ṣe fún wọn; ẹ̀rù yóo bà wọ́n, wọn yóo sì wárìrì, nítorí gbogbo nǹkan rere tí n óo máa ṣe fún ìlú náà.” OLUWA ní, “A óo tún gbọ́ ohùn ayọ̀ ati inú dídùn ninu ìlú Juda ati ìgboro Jerusalẹmu, tí ẹ sọ wí pé ó ti di ahoro, tí kò sí eniyan tabi ẹranko tó ń gbé inú wọn. A óo tún gbọ́ ohùn ọkọ iyawo ati ohùn iyawo ati ohùn àwọn tí wọn ń kọrin bí wọ́n ti ń mú ẹbọ ọpẹ́ wá sinu ilé OLUWA wí pé: 107:1; 118:1; 136:1 ‘Ẹ fi ọpẹ́ fún OLUWA àwọn ọmọ ogun, nítorí pé rere ni OLUWA, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae!’ Nítorí pé n óo dá ire wọn pada bíi ti ìgbà àtijọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA àwọn ọmọ ogun sọ pé, “Ní gbogbo ibi tí ó ti di ahoro yìí, tí eniyan tabi ẹranko kò gbé ibẹ̀, àwọn olùṣọ́-aguntan yóo sì tún máa tọ́jú àwọn agbo ẹran wọn ninu gbogbo àwọn ìlú ibẹ̀. Àwọn agbo ẹran yóo tún kọjá níwájú ẹni tí ó ń kà wọ́n ninu àwọn ìlú tí wọ́n wà ní agbègbè olókè, ati àwọn ti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣefela ati àwọn ìlú tí wọn wà ní Nẹgẹbu, ní ilẹ̀ Bẹnjamini, ní agbègbè tí ó yí Jerusalẹmu ká, ati àwọn ìlú Juda. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” Ó ní, “Àkókò ń bọ̀, tí n óo mú ìlérí tí mo ṣe fún ilé Israẹli ati ilé Juda ṣẹ. Nígbà tó bá yá, tí àkókò bá tó, n óo mú kí ẹ̀ka òdodo kan ó sọ jáde ní ilé Dafidi, yóo máa ṣe ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ati ti òdodo ní ilẹ̀ náà. A óo gba Juda là, Jerusalẹmu yóo sì wà ní àìléwu, orúkọ tí a óo wá máa pè é ni ‘OLÚWA ni Òdodo wa.’ ” Nítorí OLUWA ní kò ní sí ìgbà kan, tí kò ní jẹ́ pé ọkunrin kan ní ilé Dafidi ni yóo máa jẹ́ ọba ní ilẹ̀ Israẹli, bẹ́ẹ̀ ni kò sì ní sí ìgbà kan tí ẹnìkan ninu àwọn alufaa, ọmọ Lefi, kò ní máa dúró níwájú òun láti rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ, láti máa rú ẹbọ títí lae. OLUWA tún bá Jeremaya sọ̀rọ̀; ó ní, “Bí ẹ bá lè ba majẹmu tí mo bá ọ̀sán ati òru dá jẹ́, tí wọn kò fi ní wà ní àkókò tí mo yàn fún wọn mọ́, òun nìkan ni majẹmu tí mo bá Dafidi iranṣẹ mi dá ṣe lè yẹ̀, tí ìdílé rẹ̀ kò fi ní máa ní ọmọkunrin kan tí yóo jọba; bẹ́ẹ̀ náà ni majẹmu tí mo bá àwọn alufaa, ọmọ Lefi iranṣẹ mi dá. Bí a kò ti ṣe lè ka iye ìràwọ̀ ojú ọ̀run, tí a kò sì lè wọn yanrìn etí òkun, bẹ́ẹ̀ ní n óo ṣe sọ arọmọdọmọ Dafidi ati arọmọdọmọ Lefi alufaa, iranṣẹ mi, di pupọ.” OLUWA bi Jeremaya pé: “Ṣé o kò gbọ́ ohun tí àwọn eniyan wọnyi ń sọ tí wọn ní, ‘OLUWA ti kọ ìdílé mejeeji tí ó yàn sílẹ̀?’ Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń fojú tẹmbẹlu àwọn eniyan mi, títí tí wọn kò fi dàbí orílẹ̀-èdè lójú wọn mọ́. Bí n kò bá tíì fìdí majẹmu mi múlẹ̀ pẹlu ọ̀sán ati òru, tí n kò sì ṣe ìlànà fún ọ̀run ati ayé, òun nìkan ni n óo fi kọ arọmọdọmọ Jakọbu ati Dafidi, iranṣẹ mi sílẹ̀, tí n kò fi ní máa yan ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ láti jọba lórí ìran Abrahamu, Isaaki ati Jakọbu. N óo dá ire wọn pada, n óo sì ṣàánú fún wọn.” Ọ̀rọ̀ tí OLUWA bá Jeremaya sọ nìyí, nígbà tí Nebukadinesari, ọba Babiloni, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ati gbogbo ìjọba ayé tí wọ́n wà lábẹ́ rẹ̀, ati gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè gbógun ti Jerusalẹmu ati gbogbo àwọn ìlú Juda. OLUWA, Ọlọrun Israẹli ní, kí n lọ sọ fún Sedekaya, ọba Juda pé òun OLUWA ní, “Mo ṣetán tí n óo fi ìlú yìí lé ọba Babiloni lọ́wọ́; yóo sì dáná sun ún. Sedekaya, o kò ní sá àsálà, ṣugbọn wọn óo mú ọ, wọn óo fà ọ́ lé Nebukadinesari lọ́wọ́, ẹ óo rí ara yín lojukooju, ẹ óo bá ara yín sọ̀rọ̀, o óo sì lọ sí Babiloni. Sibẹsibẹ, ìwọ Sedekaya, ọba Juda OLUWA ní wọn kò ní fi idà pa ọ́. O óo fi ọwọ́ rọrí kú ni. Bí wọn ti sun turari níbi òkú àwọn baba rẹ, ati níbi òkú àwọn ọba tí wọ́n ti kú ṣáájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóo sun turari níbi òkú ìwọ náà. Wọn yóo dárò rẹ, wọn yóo máa wí pé, ‘Ó ṣe, oluwa mi,’ nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA ṣe ìlérí; èmi ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” Jeremaya wolii bá sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà fún Sedekaya ọba Juda, ní Jerusalẹmu, ní àkókò tí àwọn ọmọ ogun ọba Babiloni gbógun ti Jerusalẹmu ati Lakiṣi ati Aseka, nítorí pé àwọn nìkan ni wọ́n ṣẹ́kù ninu àwọn ìlú olódi Juda. OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí Sedekaya ọba ti bá gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu dá majẹmu pé kí wọn kéde ìdásílẹ̀, kí olukuluku dá ẹrú rẹ̀, lọkunrin ati lobinrin, tí wọ́n jẹ́ Heberu sílẹ̀, kí wọn máa lọ ní òmìnira; kí ẹnikẹ́ni má sì fi Juu arakunrin rẹ̀ ṣe ẹrú mọ́. Gbogbo àwọn ìjòyè ati àwọn ará ìlú tí wọ́n dá majẹmu yìí ni wọ́n gbọ́ràn, tí wọ́n sì dá àwọn ẹrú wọn lọkunrin ati lobinrin sílẹ̀; wọn kò sì fi wọ́n ṣe ẹrú mọ́. Ṣugbọn nígbà tó yá, wọ́n yí ọ̀rọ̀ pada, wọ́n tún mú àwọn ẹrú tí wọ́n ti dá sílẹ̀, lọkunrin ati lobinrin, wọ́n tún fi ipá sọ wọ́n di ẹrú. OLUWA wá sọ fún Jeremaya pé, “Èmi OLUWA Ọlọrun Israẹli bá àwọn baba ńlá yín dá majẹmu nígbà tí mo kó wọn jáde kúrò lóko ẹrú ní ilẹ̀ Ijipti, mo ní, lẹ́yìn ọdún meje, kí olukuluku yín máa dá ọmọ Heberu tí ó bá fi owó rà lẹ́rú sílẹ̀, lẹ́yìn tí ó bá ti sin oluwa rẹ̀ fún ọdún mẹfa. Mo ní ẹ gbọdọ̀ dá ẹrú náà sílẹ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ ní òmìnira, ṣugbọn àwọn baba ńlá yín kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu. Láìpẹ́ yìí, ẹ ronupiwada, ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú mi; ẹ kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn arakunrin yín. Ẹ dá majẹmu níwájú mi ninu ilé tí à ń fi orúkọ mi pè. Ṣugbọn ẹ tún yí ọ̀rọ̀ pada, ẹ ba orúkọ mi jẹ́ nípa pé olukuluku yín, ẹ tún mú ẹrukunrin ati ẹrubinrin tí ẹ dá sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn yín, ẹ sì tún sọ wọ́n di ẹrú pada. Nítorí náà ẹ kò gbọ́rọ̀ sí mi lẹ́nu pé kí olukuluku kéde òmìnira fún arakunrin rẹ̀ ati ọmọnikeji rẹ̀. Ẹ wò ó! N óo kéde òmìnira fun yín: òmìnira sí ọwọ́ ogun, àjàkálẹ̀ àrùn ati ìyàn, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo sì fi yín ṣe ẹrú fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé. Àwọn ọkunrin tí wọn bá rú òfin mi, tí wọn kò sì tẹ̀lé ìlànà majẹmu tí wọn dá níwájú mi, n óo bẹ́ wọn bíi ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù tí wọn bẹ́ sí meji, tí wọ́n sì gba ààrin rẹ̀ kọjá. Bí àwọn ìjòyè Juda ati àwọn ìjòyè Jerusalẹmu, àwọn ìwẹ̀fà, àwọn alufaa ati gbogbo àwọn eniyan ilẹ̀ náà ṣe bẹ́ ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù sí meji, tí wọn sì gba ààrin rẹ̀ kọjá láti bá mi dá majẹmu, ni n óo ṣe bẹ́ àwọn náà. N óo fà wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́ ati àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí wọn; òkú wọn yóo di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko. N óo fi Sedekaya, ọba Juda ati àwọn ìjòyè rẹ̀ lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́ ati àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí wọn. Wọn óo bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun ọba Babiloni tí ó ti ṣígun kúrò lọ́dọ̀ wọn. Ẹ wò ó, n óo pàṣẹ, n óo sì kó wọn pada sí ìlú yìí, wọn yóo gbógun tì í, wọn yóo gbà á; wọn yóo sì dáná sun ún. N óo sọ àwọn ìlú Juda di ahoro, kò ní sí eniyan tí yóo máa gbé inú wọn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀ ní ìgbà ayé Jehoiakimu ọmọ Josaya, ọba Juda; ó ní, “Lọ sí ilé àwọn ọmọ Rekabu kí o bá wọn sọ̀rọ̀, mú wọn wá sinu ọ̀kan ninu àwọn yàrá tí ó wà ninu ilé OLUWA, kí o sì fi ọtí lọ̀ wọ́n.” Mo bá mú Jaasanaya ọmọ Jeremaya ọmọ Habasinaya ati àwọn arakunrin rẹ̀ ati gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ ati gbogbo ìdílé Rekabu, mo mú wọn wá sinu ilé OLUWA. Mo kó wọn lọ sinu yàrá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Hanani, ọmọ Igidalaya eniyan Ọlọrun, yàrá náà wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ yàrá àwọn ìjòyè, lókè yàrá Maaseaya ọmọ Ṣalumu, aṣọ́nà. Mo gbé ìgò ọtí kalẹ̀ níwájú àwọn ọmọ Rekabu, mo kó ife tì í. Mo bá sọ fún wọn pé, “Ó yá, ẹ máa mu ọtí waini.” Ṣugbọn wọ́n dáhùn pé, “A kò ní mu ọtí kankan nítorí pé Jonadabu, baba ńlá wa tíí ṣe ọmọ Rekabu ti pàṣẹ fún wa pé a kò gbọdọ̀ mu ọtí, ati àwa ati arọmọdọmọ wa títí lae. A kò gbọdọ̀ kọ́ ilé, a kò gbọdọ̀ dá oko, a kò gbọdọ̀ gbin ọgbà àjàrà. Ó ní inú àgọ́ ni kí á máa gbé ní gbogbo ọjọ́ ayé wa, kí ọjọ́ wa baà lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí à ń gbé. A gbọ́ràn sí Jonadabu baba ńlá wa lẹ́nu, à ń pa gbogbo àṣẹ tí ó pa fún wa mọ́, pé kí á má mu ọtí ní gbogbo ọjọ́ ayé wa, àwa, àwọn aya wa ati àwọn ọmọ wa lọkunrin ati lobinrin. Ó ní a kò gbọdọ̀ kọ́ ilé tí a óo máa gbé. A kò ṣe ọgbà àjàrà, tabi kí á dá oko, tabi kí á gbin ohun ọ̀gbìn. Inú àgọ́ ni à ń gbé, a sì pa gbogbo àṣẹ tí Jonadabu baba ńlá wa fún wa mọ́. Ṣugbọn nígbà tí Nebukadinesari, ọba Babiloni gbógun ti ilẹ̀ yìí, a wí fún ara wa pé kí á wá sí Jerusalẹmu nítorí ìbẹ̀rù àwọn ọmọ ogun, àwọn ará Kalidea ati ti àwọn ará Siria. Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe di ẹni tí ń gbé Jerusalẹmu.” OLUWA bá sọ fún Jeremaya pé, “Èmi OLUWA, àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní kí o lọ sọ fún àwọn ará Juda ati àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu pé, ṣé wọn kò ní gba ẹ̀kọ́ kí wọn sì fetí sí ọ̀rọ̀ mi ni? Àwọn ọmọ Rekabu pa òfin tí Jonadabu, baba ńlá wọn, fún wọn mọ́, pé kí wọn má mu ọtí waini, wọn kò sì mu ọtí rárá títí di òní olónìí, nítorí pé wọ́n pa àṣẹ baba ńlá wọn mọ́. Mo ti bá yín sọ̀rọ̀ ní ọpọlọpọ ìgbà, ṣugbọn ẹ kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu. Mo ti rán gbogbo àwọn iranṣẹ mi, àwọn wolii, si yín, ní ọpọlọpọ ìgbà pé kí olukuluku yín yipada kúrò ní ọ̀nà burúkú tí ó ń tọ̀, kí ẹ tún ìwà yín ṣe, kí ẹ má sá tẹ̀lé àwọn oriṣa kiri, kí ẹ yé máa sìn wọ́n; kí ẹ lè máa gbé ilẹ̀ tí mo fún ẹ̀yin ati àwọn baba ńlá yín. Ṣugbọn ẹ kò fetí sí ọ̀rọ̀ mi, ẹ kò sì gbọ́ràn sí mi lẹ́nu. Àwọn ọmọ Jonadabu, ọmọ Rekabu mú àṣẹ baba ńlá wọn tí ó pa fún wọn ṣẹ, ṣugbọn àwọn eniyan wọnyi kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu. Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli, ni mo sọ pé n óo jẹ́ kí ibi bá àwọn ará Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu, nítorí pé mo bá wọn sọ̀rọ̀, wọn kò gbọ́; mo pè wọ́n, wọn kò dáhùn.” Ṣugbọn Jeremaya sọ fún àwọn ọmọ Rekabu pé, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, ‘Nítorí pé ẹ gbọ́ràn sí Jonadabu baba ńlá yín lẹ́nu, ẹ sì pa gbogbo òfin rẹ̀ mọ́, ẹ sì ń ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pàṣẹ pé kí ẹ máa ṣe, nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní títí lae, kò ní sí ìgbà kan tí Jonadabu, ọmọ Rekabu kò ní ní ẹnìkan tí yóo máa ṣe iṣẹ́ ìsìn níwájú mi.’ ” Ní ọdún kẹrin ìjọba Jehoiakimu ọmọ Josaya ọba Juda, OLUWA sọ fún Jeremaya pé, “Mú ìwé kíká kí o sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún ọ nípa Israẹli ati Juda ati gbogbo orílẹ̀-èdè sinu rẹ̀. Gbogbo ohun tí mo sọ láti ọjọ́ tí mo ti ń bá ọ sọ̀rọ̀ ní ìgbà ayé Josaya títí di òní, ni kí o kọ. Bóyá bí àwọn ará Juda bá gbọ́ nípa ibi tí mò ń gbèrò láti ṣe sí wọn, olukuluku lè yipada kúrò ninu ọ̀nà ibi rẹ̀, kí n lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ati àìdára wọn jì wọ́n.” Jeremaya bá pe Baruku ọmọ Neraya, ó sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí OLUWA bá a sọ fún un, Baruku bá kọ wọ́n sinu ìwé kíká kan. Jeremaya pàṣẹ fún Baruku pé, “Wọn kò gbà mí láàyè láti lọ sí inú ilé OLUWA; nítorí náà, ìwọ ni óo lọ sibẹ ní ọjọ́ ààwẹ̀ láti ka ọ̀rọ̀ tí o gbọ́ ní ẹnu mi; tí o sì kọ sí inú ìwé kíká, sí etí gbogbo àwọn ará Juda tí wọ́n wá láti ìlú wọn. Ó ṣeéṣe kí wọn mú ẹ̀bẹ̀ wọn wá siwaju OLUWA, kí olukuluku sì yipada kúrò lọ́nà ibi rẹ̀ tí ó ń rìn, nítorí pé ibinu OLUWA pọ̀ lórí wọn.” Baruku bá ṣe gbogbo ohun tí Jeremaya wolii pa láṣẹ fún un lati kà lati inú ìwé ilé Oluwa. Ní oṣù kẹsan-an, ọdún karun-un tí Jehoiakimu ọmọ Josaya jọba ní Juda, gbogbo àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu ati àwọn eniyan tí wọ́n ti àwọn ìlú Juda wá sí Jerusalẹmu, kéde ọjọ́ ààwẹ̀ níwájú OLUWA. Baruku bá ka ọ̀rọ̀ Jeremaya tí ó kọ sinu ìwé, sí etígbọ̀ọ́ gbogbo eniyan ní yàrá Gemaraya, ọmọ Ṣafani, akọ̀wé, tí ó wà ní gbọ̀ngàn òkè ní Ẹnu Ọ̀nà Titun ilé OLUWA. Nígbà tí Mikaaya ọmọ Gemaraya, ọmọ Ṣafani gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ OLUWA tí ó wà ninu ìwé náà; Ó lọ sí yàrá akọ̀wé ní ààfin ọba, ó bá gbogbo àwọn ìjòyè tí wọn jókòó níbẹ̀: Eliṣama akọ̀wé ati Delaaya ọmọ Ṣemaaya, ati Elinatani ọmọ Akibori, ati Gemaraya ọmọ Ṣafani, ati Sedekaya ọmọ Hananaya ati gbogbo àwọn ìjòyè. Mikaaya sọ gbogbo ohun tí ó gbọ́, nígbà tí Baruku ka ohun tí ó kọ sinu ìwé fún wọn. Gbogbo àwọn ìjòyè bá rán Jehudi ọmọ Netanaya, ọmọ Ṣelemaya ọmọ Kuṣi pé kí ó lọ sọ fún Baruku kí ó máa bọ̀ kí ó sì mú ìwé tí ó kà sí etígbọ̀ọ́ gbogbo eniyan lọ́wọ́. Baruku, ọmọ Neraya, sì wá sọ́dọ̀ wọn tòun ti ìwé náà lọ́wọ́ rẹ̀. Wọ́n ní kí ó jókòó, kí ó kà á fún àwọn, Baruku bá kà á fún wọn. Nígbà tí wọ́n gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ náà, ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wo ara wọn lójú. Wọ́n bá sọ fún Baruku pé, “A gbọdọ̀ sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí fún ọba.” Wọ́n bi Baruku pé, “Sọ fún wa, báwo ni o ṣe kọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi sílẹ̀? Ṣé Jeremaya ni ó sọ ọ́, tí ìwọ fi ń kọ ọ́ ni, àbí báwo?” Baruku bá dá wọn lóhùn pé, Jeremaya ni ó sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà fún òun ni òun fi kọ ọ́ sinu ìwé. Àwọn ìjòyè bá sọ fún Baruku pé kí òun ati Jeremaya lọ sápamọ́, kí wọn má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ ibi tí wọ́n wà. Àwọn ìjòyè bá fi ìwé náà pamọ́ sinu yàrá Eliṣama akọ̀wé, lẹ́yìn náà wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ ọba ní gbọ̀ngàn, wọ́n sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà fún un. Ọba bá rán Jehudi pé kí ó lọ mú ìwé náà wá, ó sì mú un wá láti inú yàrá Eliṣama, akọ̀wé. Jehudi bá kà á fún ọba ati gbogbo àwọn ìjòyè tí wọn dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ninu oṣù kẹsan-an ni ọ̀rọ̀ yìí ṣẹlẹ̀, ọba sì wà ní ilé tíí máa gbé ní àkókò òtútù, iná kan sì wà níwájú rẹ̀ tí ń jó ninu agbada. Bí Jehudi bá ti ka òpó mẹta tabi mẹrin ninu ìwé náà, ọba yóo fi ọ̀bẹ gé e kúrò, yóo sì jù ú sinu iná tí ń jó níwájú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe títí ó fi fi ìwé náà jóná tán. Sibẹ ẹ̀rù kò ba ọba tabi àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí wọ́n gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí, wọn kò sì fa aṣọ wọn ya. Elinatani, Dilaaya ati Gemaraya tilẹ̀ bẹ ọba pé kí ó má fi ìwé náà jóná, ṣugbọn kò gbà. Ọba bá pàṣẹ fún Jerameeli ọmọ rẹ̀, ati Seraaya ọmọ Asirieli, ati Ṣelemaya ọmọ Abideeli, pé kí wọn lọ mú Baruku akọ̀wé, ati Jeremaya wolii wá, ṣugbọn OLUWA fi wọ́n pamọ́. Lẹ́yìn tí ọba ti fi ìwé náà jóná, ati gbogbo ohun tí Jeremaya ní kí Baruku kọ sinu rẹ̀, OLUWA sọ fún Jeremaya pé, “Mú ìwé mìíràn kí o tún kọ gbogbo ohun tí ó wà ninu ìwé ti àkọ́kọ́, tí Jehoiakimu, ọba Juda fi jóná sinu rẹ̀. Ohun tí o óo kọ nípa Jehoiakimu ọba Juda, nìyí: sọ pé èmi OLUWA ní, ṣé ó fi ìwé ti àkọ́kọ́ jóná ni, ó ní, kí ló dé tí a fi kọ sinu rẹ̀ pé dájúdájú, ọba Babiloni ń bọ̀ wá pa ilẹ̀ yìí run ati pé, yóo pa ati eniyan ati ẹranko tí ó wà ninu rẹ̀ run? Nítorí náà, ohun tí èmi OLUWA níí sọ nípa rẹ̀ ni pé, ẹyọ ọmọ rẹ̀ kan kò ní jọba lórí ìtẹ́ Dafidi. Ìta ni a óo gbé òkú rẹ̀ jù sí, oòrùn yóo máa pa á lọ́sàn-án, ìrì yóo sì máa sẹ̀ sí i lórí lóru. N óo jẹ òun, ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ níyà, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. N óo mú kí gbogbo ibi tí mo pinnu lórí wọn ṣẹ sí wọn lára ati sí ara àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu ati àwọn ará Juda, nítorí pé wọn kò gbọ́ràn.” Jeremaya bá fún Baruku akọ̀wé, ọmọ Neraya, ní ìwé mìíràn, Baruku sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jeremaya sọ fún un sinu rẹ̀. Ó kọ ohun tí ó wà ninu ìwé àkọ́kọ́ tí Jehoiakimu ọba Juda fi jóná, ó sì fi àwọn nǹkan mìíràn kún un pẹlu. Nebukadinesari, ọba Babiloni fi Sedekaya, ọmọ Josaya, jọba ní ilẹ̀ Juda dípò Jehoiakini, ọmọ Jehoiakimu. Ṣugbọn Sedekaya ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ati àwọn eniyan náà kò pa ọ̀rọ̀ tí OLUWA ní kí Jeremaya wolii sọ fún wọn mọ́. Ọba Sedekaya rán Jehukali, ọmọ Ṣelemaya, ati Sefanaya, alufaa, ọmọ Maaseaya, sí Jeremaya wolii, pé kí ó jọ̀wọ́ bá àwọn gba adura sí OLUWA Ọlọrun. Ní àkókò yìí Jeremaya sì ń rìn káàkiri láàrin àwọn eniyan, nítorí wọn kò tíì jù ú sẹ́wọ̀n nígbà náà. Àwọn ọmọ ogun Farao ti jáde, wọ́n ń bọ̀ láti Ijipti; nígbà tí àwọn ará Kalidea tí wọn dóti Jerusalẹmu gbọ́ pé wọ́n ń bọ̀, wọ́n kúrò ní Jerusalẹmu. OLUWA sọ fún Jeremaya wolii pé kí ó sọ fún àwọn tí ọba Juda rán láti wá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ pé, OLUWA Ọlọrun Israẹli ní kí òun Jeremaya sọ fún ọba pé, àwọn ọmọ ogun Farao tí wọn wá ràn wọ́n lọ́wọ́ ti ń múra láti pada sí Ijipti, ilẹ̀ wọn. Àwọn ará Kalidea sì ń pada bọ̀ wá gbé ogun ti ìlú yìí; wọn yóo gbà á, wọn yóo sì dáná sun ún. OLUWA ní kí wọn sọ fún Sedekaya ati àwọn ará Juda kí wọn má tan ara wọn jẹ, kí wọn má sì rò pé àwọn ará Kalidea kò ní pada wá sọ́dọ̀ wọn mọ́, nítorí wọn kò ní lọ. Bí àwọn ará Juda bá tilẹ̀ ṣẹgun gbogbo ọmọ ogun àwọn ará Kalidea, tí wọ́n gbógun tì wọ́n, títí tí ó fi jẹ́ pé àwọn tí wọ́n ti fara gbọgbẹ́ nìkan ni wọ́n kù ninu àgọ́ wọn, wọn yóo dìde sí àwọn ará Juda, wọn yóo sì sun ìlú yìí níná. Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ogun Kalidea ti kúrò ní Jerusalẹmu, nígbà tí wọ́n rí i pé àwọn ọmọ ogun Farao ń bọ̀, Jeremaya jáde ní Jerusalẹmu ó fẹ́ lọ sí ilẹ̀ Bẹnjamini kí ó lọ gba ilẹ̀ rẹ̀ kan lọ́wọ́ àwọn eniyan tí wọ́n wà níbẹ̀. Bí Jeremaya wolii ti dé bodè Bẹnjamini ọ̀kan ninu àwọn oníbodè tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Irija ọmọ Ṣelemaya ọmọ Hananaya mú un, ó ní, “O fẹ́ sálọ bá àwọn ará Kalidea ni.” Jeremaya dá a lóhùn, pé, “Rárá o, n kò sálọ sọ́dọ̀ àwọn ará Kalidea.” Ṣugbọn Irija kọ̀, kò gbọ́, ó sá mú Jeremaya lọ sọ́dọ̀ àwọn ìjòyè. Inú bí àwọn ìjòyè sí Jeremaya, wọ́n lù ú, wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n ní ilé Jonatani akọ̀wé, nítorí pé wọ́n ti sọ ibẹ̀ di ọgbà ẹ̀wọ̀n. Lẹ́yìn tí Jeremaya ti wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n fún ọpọlọpọ ọjọ́, Sedekaya ọba ranṣẹ lọ mú un wá sí ààfin rẹ̀, ó sì fi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò níkọ̀kọ̀, ó ní, “Ǹjẹ́ OLUWA ranṣẹ kankan?” Jeremaya dáhùn, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ ni, ohun tí OLUWA sọ ni pé, a óo fi ọ́ lé ọba Babiloni lọ́wọ́.” Jeremaya wá bi Sedekaya ọba pé, “Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ ọ́, tabi àwọn ẹmẹ̀wà rẹ, tabi àwọn ará ìlú yìí, tí ẹ fi jù mí sẹ́wọ̀n? Níbo ni àwọn wolii rẹ wà, àwọn tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún ọ pé, ‘Ọba Babiloni kò ní gbógun ti ìwọ ati ilẹ̀ yìí?’ Nisinsinyii, kabiyesi, oluwa mi, jọ̀wọ́ fetí sí ẹ̀bẹ̀ mi, má dá mi pada sí ilé Jonatani akọ̀wé, kí n má baà kú sibẹ.” Sedekaya ọba bá pàṣẹ, wọ́n sì fi Jeremaya sinu gbọ̀ngàn ọgbà àwọn tí ń ṣọ́ ààfin. Wọ́n sì ń fún un ní burẹdi kan lojumọ láti òpópónà àwọn oníburẹdi títí tí gbogbo burẹdi fi tán ní ìlú. Bẹ́ẹ̀ ni Jeremaya ṣe bẹ̀rẹ̀ sí gbé gbọ̀ngàn àwọn tí ń ṣọ́ ààfin. Nígbà tí Ṣefataya, ọmọ Matani, ati Gedalaya, ọmọ Paṣuri, ati Jukali, ọmọ Ṣelemaya, ati Paṣuri ọmọ Malikaya gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Jeremaya ń sọ fún gbogbo àwọn eniyan pé, “OLUWA ní, ẹni tí ó bá dúró ní ìlú Jerusalẹmu yóo kú ikú idà, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn; ṣugbọn àwọn tí wọn bá jáde tọ àwọn ará Kalidea lọ yóo yè. Ó ní ọ̀rọ̀ wọn yóo dàbí ẹni tí ó ja àjàbọ́, ṣugbọn yóo wà láàyè. Ati pé dájúdájú, ìlú yìí yóo bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun Babiloni, wọn yóo sì gbà á.” Àwọn ìjòyè náà bá sọ fún ọba pé, “Ẹ jẹ́ kí á pa ọkunrin yìí nítorí pé ó ń mú ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ ogun tí wọn kù láàrin ìlú, ati gbogbo àwọn eniyan nítorí irú ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ fún wọn. Ọkunrin yìí kò fẹ́ alaafia àwọn eniyan wọnyi, àfi ìpalára wọn.” Sedekaya ọba bá dá wọn lóhùn, pé, “Ìkáwọ́ yín ló wà, n kò jẹ́ ṣe ohunkohun tí ó bá lòdì sí ìfẹ́ yín.” Wọ́n bá mú Jeremaya, wọ́n jù ú sinu kànga Malikaya, ọmọ ọba, tí ó wà ní gbọ̀ngàn àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin. Wọ́n fi okùn sọ Jeremaya kalẹ̀ sinu kànga náà, kò sí omi ninu rẹ̀, àfi ẹrẹ̀ nìkan, Jeremaya sì rì sinu ẹrẹ̀ náà. Nígbà tí Ebedimeleki ará Etiopia tí ó jẹ́ ìwẹ̀fà ní ààfin ọba gbọ́ pé wọ́n ti ju Jeremaya sinu kànga. Ọba wà níbi tí ó jókòó sí ní ibodè Bẹnjamini. Ebedimeleki jáde ní ààfin, ó lọ bá ọba ó sì wí fún un pé, “Kabiyesi, oluwa mi, gbogbo nǹkan tí àwọn eniyan wọnyi ṣe sí wolii Jeremaya kò dára. Inú kànga ni wọ́n jù ú sí, ebi ni yóo sì pa á sibẹ nítorí pé kò sí burẹdi ní ìlú mọ́.” Ọba bá pàṣẹ fún Ebedimeleki ará Etiopia, ó ní, “Mú eniyan mẹta lọ́wọ́, kí ẹ lọ yọ Jeremaya wolii kúrò ninu kànga náà kí ó tó kú.” Ebedimeleki bá mú àwọn ọkunrin mẹta náà, wọ́n lọ sí yàrá kan ní ilé ìṣúra tí ó wà láàfin ọba. Ó mú àwọn àkísà ati àwọn aṣọ tí wọ́n ti gbó níbẹ̀, ó so okùn mọ́ wọn, ó sì nà án sí Jeremaya ninu kànga. Ó bá sọ fún Jeremaya pé kí ó fi àwọn àkísà ati àwọn aṣọ tí wọ́n ti gbó náà sí abíyá mejeeji, kí ó fi okùn kọ́ ara rẹ̀ lábíyá. Jeremaya sì ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n bá fi okùn fa Jeremaya jáde kúrò ninu kànga. Jeremaya bá ń gbé gbọ̀ngàn àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin. Sedekaya ọba ranṣẹ lọ mú Jeremaya wolii wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà kẹta tí ó wà ní Tẹmpili OLUWA, ó wí fún Jeremaya pé, “Ọ̀rọ̀ kan ni mo fẹ́ bèèrè lọ́wọ́ rẹ, má sì fi ohunkohun pamọ́ fún mi.” Jeremaya bá wí fún Sedekaya, ó ní, “Bí mo bá sọ fún ọ, o kò ní pa mí dájúdájú? Bí mo bá sì fún ọ ní ìmọ̀ràn, o kò ní gbà.” Sedekaya ọba bá búra fún Jeremaya ní ìkọ̀kọ̀ pé, “Mo fi OLUWA alààyè ẹni tí ó dá ẹ̀mí wa búra, pé n kò ní pa ọ́, n kò sì ní fi ọ́ lé àwọn tí wọn ń wá ọ̀nà láti pa ọ́ lọ́wọ́.” Jeremaya bá wí fún Sedekaya pé, “OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, bí o bá jọ̀wọ́ ara rẹ fún àwọn ìjòyè ọba Babiloni, wọn ó dá ẹ̀mí rẹ sí, wọn kò sì ní dáná sun ìlú yìí, ìwọ ati àwọn ará ilé rẹ yóo sì yè. Ṣugbọn bí o kò bá fi ara rẹ le àwọn ìjòyè ọba Babiloni lọ́wọ́, ìlú yìí yóo bọ́ sọ́wọ́ àwọn ará Kalidea, wọn yóo sì dáná sun ún, ìwọ pàápàá kò sì ní bọ́ lọ́wọ́ wọn.” Sedekaya ọba bá wí fún Jeremaya pé, “Ẹ̀rù àwọn ará Juda tí wọ́n sá lọ bá àwọn ará Kalidea ń bà mí. Wọ́n lè fà mí lé wọn lọ́wọ́, kí wọ́n sì fi mí ṣẹ̀sín.” Jeremaya dáhùn pé, “Wọn kò ní fà ọ́ lé wọn lọ́wọ́. Tẹ̀lé ọ̀rọ̀ OLUWA tí mò ń sọ fún ọ; yóo dára fún ọ, a óo sì dá ẹ̀mí rẹ sí. Ṣugbọn bí o bá kọ̀ láti jọ̀wọ́ ara rẹ ohun tí OLUWA fihàn mí nìyí: Wò ó, mo rí i tí wọn ń kó àwọn obinrin tí wọ́n wà ní ààfin ọba Juda jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ìjòyè ọba Babiloni, wọ́n sì ń wí pé, ‘Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí o fọkàn tán tàn ọ́, wọ́n sì ti ṣẹgun rẹ; nisinsinyii tí o rì sinu ẹrẹ̀, wọ́n pada lẹ́yìn rẹ.’ “Gbogbo àwọn aya rẹ ati àwọn ọmọ rẹ ni wọn yóo kó lọ sọ́dọ̀ àwọn ará Kalidea, ìwọ gan-an kò sì ní bọ́ lọ́wọ́ wọn. Ọwọ́ ọba Babiloni yóo tẹ̀ ọ́, wọn yóo sì dáná sun ìlú yìí.” Sedekaya ọba bá kìlọ̀ fún Jeremaya pé, “Má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ gbogbo nǹkan tí a jọ sọ, o kò sì ní kú. Bí àwọn ìjòyè bá gbọ́ pé a jọ sọ̀rọ̀, bí wọn bá wá sọ́dọ̀ rẹ tí wọn ní kí o sọ nǹkan tí o bá mi sọ fún àwọn, ati èsì tí mo fún ọ, tí wọn bẹ̀ ọ́ pé kí o má fi ohunkohun pamọ́ fún àwọn, tí wọn sì ṣe ìlérí pé àwọn kò ní pa ọ́, sọ fún wọn pé ẹ̀bẹ̀ ni ò ń bẹ̀ mí pé kí n má dá ọ pada sí ilé Jonatani; kí o má baà kú sibẹ.” Gbogbo àwọn ìjòyè tọ Jeremaya lọ, wọ́n bí í, ó sì fún wọn lésì gẹ́gẹ́ bí ọba tí pàṣẹ fún un. Wọ́n bá dákẹ́, nítorí ẹnikẹ́ni kò gbọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n jọ sọ. Jeremaya bá ń gbé gbọ̀ngàn àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin títí di ọjọ́ tí ogun kó Jerusalẹmu. Ní oṣù kẹwaa, ọdún kẹsan-an ìjọba Sedekaya, ọba Juda, Nebukadinesari, ọba Babiloni, ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti Jerusalẹmu, wọ́n sì dótì í. Ní ọjọ́ kẹsan-an, oṣù kẹrin, ọdún kọkanla ìjọba rẹ̀, wọ́n wọ ìlú náà. Lẹ́yìn tí ogun ti kó Jerusalẹmu, gbogbo àwọn ìjòyè ọba Babiloni péjọ, wọ́n sì jókòó ní bodè ààrin: Negali Sareseri, Samgari Nebo, Sarisekimu Rabusarisi, Negali Sareseri, Rabumagi ati àwọn ìjòyè ọba Babiloni yòókù. Nígbà tí Sedekaya ọba Juda ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ rí wọn, wọ́n sá. Wọ́n fòru bojú, wọ́n bá jáde ní ìlú; wọ́n gba ọ̀nà ọgbà ọba, ní ọ̀nà ibodè tí ó wà láàrin odi meji, wọ́n sì dojú kọ ọ̀nà Araba. Ṣugbọn àwọn ọmọ ogun Kalidea lé wọn, wọ́n bá Sedekaya ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹriko; wọ́n mú un lọ sí ọ̀dọ̀ Nebukadinesari ọba Babiloni ní Ribila ní ilẹ̀ Hamati, ó sì dá Sedekaya lẹ́jọ́. Ọba Babiloni pa àwọn ọmọ Sedekaya ní Ribila níṣojú rẹ̀, ó sì pa gbogbo àwọn ìjòyè Juda pẹlu. Ó yọ ojú Sedekaya, ó sì fi ẹ̀wọ̀n bàbà dè é láti mú un lọ sí Babiloni. Àwọn ará Kalidea jó ààfin ọba ati ilé àwọn ará ìlú, wọ́n sì wó odi Jerusalẹmu lulẹ̀. Nebusaradani olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ bá kó àwọn eniyan tí wọn ṣẹ́kù ní Jerusalẹmu ní ìgbèkùn, lọ sí Babiloni pẹlu àwọn tí wọn kọ́ sá lọ bá a tẹ́lẹ̀. Nebusaradani olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ fi díẹ̀ ninu àwọn talaka sílẹ̀ ní ilẹ̀ Juda, ó sì fún wọn ní ọgbà àjàrà ati oko. Nebukadinesari ọba Babiloni pàṣẹ fún Nebusaradani olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ pé kí wọn mú Jeremaya, kí wọn tọ́jú rẹ̀ dáradára, kí wọn má pa á lára, ṣugbọn kí wọn ṣe ohunkohun tí ó bá ń fẹ́ fún un. Nebusaradani olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ ati Nebuṣasibani, ìjòyè pataki kan, ati Negali Sareseri olóyè pataki mìíràn ati gbogbo àwọn olóyè jàǹkànjàǹkàn ninu àwọn ìjòyè ọba Babiloni, wọ́n ranṣẹ lọ mú Jeremaya jáde kúrò ní ìgbèkùn. Wọ́n bá fà á lé Gedalaya ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani lọ́wọ́, pé kí ó mú un lọ sí ilé rẹ̀. Ó bá ń gbé ààrin àwọn eniyan náà. OLUWA sọ fún Jeremaya nígbà tí ó wà ní àtìmọ́lé ní gbọ̀ngàn àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin ọba, pé, kí ó lọ sọ fún Ebedimeleki ará Etiopia pé, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, “Wò ó, n óo mú ìpinnu ibi tí mo ṣe lórí ìlú yìí ṣẹ, lójú rẹ ni yóo sì ṣẹ. N óo gbà ọ́ sílẹ̀ ní ọjọ́ náà, wọn kò ní fà ọ́ lé àwọn tí ò ń bẹ̀rù lọ́wọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Nítorí pé, dájúdájú n óo gbà ọ́ sílẹ̀, o ò ní kú ikú idà, ṣugbọn o óo sá àsálà, nítorí pé o gbẹ́kẹ̀lé mi.” OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí Nebusaradani, olórí àwọn tí ń ṣọ́ ọba Babiloni, tú u sílẹ̀ ní Rama. Nebusaradani rí Jeremaya tí wọ́n fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè é, wọ́n sì kó o pọ̀ mọ́ àwọn tí wọn kó kúrò ní ìlú Jerusalẹmu ati ní ilẹ̀ Juda tí wọn ń kó lọ sí Babiloni. Nebusaradani, olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba Babiloni, sọ fún Jeremaya pé, “OLUWA Ọlọrun rẹ ti pinnu láti ṣe ilẹ̀ yìí ní ibi; Ó sì ti ṣe bí ó ti pinnu nítorí pé ẹ dẹ́ṣẹ̀ sí i, ẹ kò sì fetí sí ohùn rẹ̀, nítorí náà ni ibi ṣe dé ba yín. Nisinsinyii, wò ó, mo tú ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ ọwọ́ rẹ sílẹ̀, bí o bá fẹ́ bá mi lọ sí Babiloni, máa bá mi kálọ, n óo tọ́jú rẹ dáradára; bí o kò bá sì fẹ́ lọ, dúró. Wò ó, gbogbo ilẹ̀ nìyí níwájú rẹ yìí, ibi tí o bá fẹ́ tí ó dára lójú rẹ ni kí o lọ. Bí o bá fẹ́ pada, pada lọ bá Gedalaya ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ẹni tí ọba Babiloni fi ṣe gomina àwọn ìlú Juda, kí o máa bá a gbé láàrin àwọn eniyan náà. Bí o kò bá sì fẹ́ bẹ́ẹ̀, ibi tí ó bá wù ọ́ láti lọ ni kí o lọ.” Olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba bá fún un ní owó, oúnjẹ, ati ẹ̀bùn, ó ní kí ó máa lọ. Jeremaya bá pada sọ́dọ̀ Gedalaya, ọmọ Ahikamu ní Misipa, ó sì ń gbé pẹlu rẹ̀ láàrin àwọn eniyan tí wọn kù ní ilẹ̀ náà. Nígbà tí gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà ní ìgbèríko pẹlu àwọn ọmọ ogun wọn gbọ́ pé ọba Babiloni ti fi Gedalaya ọmọ Ahikamu jẹ gomina ní ilẹ̀ Juda, ati pé ó ti fi ṣe olùtọ́jú àwọn ọkunrin, ati àwọn obinrin, ati àwọn ọmọde ati díẹ̀ ninu àwọn talaka ilẹ̀ Juda, tí wọn kò kó lọ sí Babiloni, wọ́n lọ bá Gedalaya ní Misipa. Àwọn tí wọ́n lọ nìwọ̀nyí: Iṣimaeli, ọmọ Netanaya, Johanani, ọmọ Karea, Seraaya, ọmọ Tanhumeti, àwọn ọmọ Efai, ará Netofa, Jesanaya, ọmọ ará Maakati, àwọn àtàwọn eniyan wọn. Gedalaya bá búra fún àwọn ati àwọn eniyan wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù ati sin àwọn ará Kalidea. Ẹ máa gbé ilẹ̀ yìí, kí ẹ máa sin ọba Babiloni, yóo sì dára fun yín. Ní tèmi, Misipa ni n óo máa gbé kí n lè máa rí ààyè bá àwọn ará Kalidea tí wọn wá dótì wá sọ̀rọ̀. Ẹ̀yin ẹ máa kó ọtí, èso, ati òróró jọ sinu ìkòkò yín, kí ẹ sì máa gbé àwọn ìlú tí ẹ ti gbà.” Bákan náà, nígbà tí gbogbo àwọn ará Juda tí wọn wà ní ilẹ̀ Moabu, ati àwọn tí wọn wà ní ilẹ̀ àwọn ará Amoni ati ti Edomu ati àwọn tí wọ́n wà ní gbogbo ilẹ̀ káàkiri gbọ́ pé ọba Babiloni dá àwọn eniyan díẹ̀ sí ní Juda, àtipé ó fi Gedalaya, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ṣe gomina wọn, gbogbo àwọn ará Juda pada láti gbogbo ibi tí wọn sá lọ, wọ́n wá sí ilẹ̀ Juda, wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ Gedalaya ní Misipa, wọ́n sì kó ọtí ati èso jọ lọpọlọpọ. Johanani ọmọ Karea ati gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà ní ìgbèríko wá sọ́dọ̀ Gedalaya ní Misipa. Wọ́n sọ fún un pé, “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Baalisi, ọba àwọn ọmọ Amoni ti rán Iṣimaeli, ọmọ Netanaya pé kí ó wá pa ọ́?” Ṣugbọn Gedalaya kò gbà wọ́n gbọ́. Johanani bá sọ fún Gedalaya ní ìkọ̀kọ̀ ní Misipa pé, “Jẹ́ kí n lọ pa Iṣimaeli ọmọ Netanaya, ẹnikẹ́ni kò sì ní mọ̀. Kí ló dé tí o óo jẹ́ kí ó pa ọ́, tí gbogbo Juda tí wọn kóra jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ yóo sì túká; tí àwọn tí wọn ṣẹ́kù ninu àwọn eniyan Juda yóo sì ṣègbé?” Ṣugbọn Gedalaya sọ fún Johanani, ọmọ Karea pé, “Má ṣe bẹ́ẹ̀, irọ́ ni ò ń pamọ́ Iṣimaeli.” Ní oṣù keje ni Iṣimaeli, ọmọ Netanaya ọmọ Eliṣama dé, ìdílé ọba ni ó ti wá, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìjòyè ọba. Òun pẹlu àwọn ọkunrin mẹ́wàá bá lọ sọ́dọ̀ Gedalaya ọmọ Ahikamu ní Misipa. Bí wọ́n ṣe ń jẹun lọ́wọ́ ní Misipa, Iṣimaeli, ọmọ Netanaya ati àwọn mẹ́wàá tí wọ́n bá a wá dìde, wọ́n bá fi idà pa Gedalaya tí ọba Babiloni fi ṣe gomina ilẹ̀ náà. Iṣimaeli pa gbogbo àwọn Juu tí wọ́n wà pẹlu Gedalaya ní Misipa, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun Kalidea tí wọ́n wà níbẹ̀. Ọjọ́ keji tí wọ́n pa Gedalaya tán, kí ẹnikẹ́ni tó gbọ́ nípa rẹ̀, àwọn ọgọrin eniyan kan wá láti Ṣekemu, Ṣilo ati láti Samaria pẹlu irùngbọ̀n wọn ní fífá, wọ́n fa agbádá wọn ya, wọ́n sì ṣá ara wọn lọ́gbẹ́. Wọ́n mú ọrẹ ẹbọ ati turari lọ́wọ́ wá sí Tẹmpili OLUWA. Iṣimaeli, ọmọ Netanaya sọkún pàdé wọn láti Misipa. Bí ó ti pàdé wọn ó wí pé, “Ẹ máa kálọ sí ọ̀dọ̀ Gedalaya ọmọ Ahikamu.” Nígbà tí wọ́n wọ ààrin ìlú, Iṣimaeli ọmọ Netanaya ati àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ pa wọ́n, wọ́n sì kó òkú wọn dà sí inú kòtò. Ṣugbọn àwọn mẹ́wàá kan ninu wọn sọ fún Iṣimaeli pé, “Má pa wá, nítorí a ní ọkà wíítì, ọkà baali, ati òróró ati oyin ní ìpamọ́ ninu oko.” Nítorí náà, ó fi wọ́n sílẹ̀ kò sì pa wọ́n bí ó ti pa àwọn yòókù wọn. Kòtò tí Iṣimaeli ju òkú àwọn eniyan tí ó pa sí ni kòtò tí ọba Asa gbẹ́ tí ó fi dí ọ̀nà mọ́ Baaṣa ọba Israẹli; ṣugbọn Iṣimaeli, ọmọ Netanaya fi òkú eniyan tí ó pa kún kòtò náà. Iṣimaeli bá kó gbogbo àwọn tí wọ́n kù ní Misipa lẹ́rú, àwọn ọmọ ọba lobinrin ati gbogbo àwọn tí wọ́n kù ní Misipa, àwọn tí Nebusaradani olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba fi sí abẹ́ ìṣọ́ Gedalaya. Iṣimaeli kó wọn lẹ́rú ó sì fẹ́ kó wọn kọjá sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Amoni. Nígbà tí Johanani, ọmọ Karea ati gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ gbọ́ gbogbo iṣẹ́ ibi tí Iṣimaeli, ọmọ Netanaya ṣe, wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn lọ gbógun ti Iṣimaeli, wọ́n bá a létí odò ńlá tí ó wà ní Gibeoni. Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà lọ́dọ̀ Iṣimaeli rí Johanani, ọmọ Karea ati gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, inú wọn dùn. Ni gbogbo àwọn tí Iṣimaeli kó lẹ́rú ní Misipa bá yipada kúrò lẹ́yìn rẹ̀, wọ́n lọ bá Johanani ọmọ Karea. Ṣugbọn Iṣimaeli, ọmọ Netanaya, pẹlu àwọn mẹjọ sá àsálà lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Amoni. Lẹ́yìn náà Johanani ọmọ Karea, ati gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, kó gbogbo àwọn tí Iṣimaeli ọmọ Netanaya kó lẹ́rú ní Misipa, lẹ́yìn tí ó pa Gedalaya ọmọ Ahikamu tán, ó bá kó ati àwọn ọmọ ogun, ati àwọn obinrin, ati àwọn ọmọde, ati àwọn ìwẹ̀fà, pada wá láti Gibeoni. Wọ́n lọ ń gbé Geruti Kimhamu, tí ó wà lẹ́bàá Bẹtilẹhẹmu. Wọ́n pinnu láti kó lọ sí ilẹ̀ Ijipti nítorí ẹ̀rù àwọn ará Kalidea ń bà wọ́n; nítorí pé Iṣimaeli ọmọ Netanaya ti pa Gedalaya, ọmọ Ahikamu, tí ọba Babiloni fi ṣe gomina ilẹ̀ náà. Lẹ́yìn náà gbogbo àwọn olórí ogun ati Johanani, ọmọ Karea ati Asaraya, ọmọ Hoṣaaya, ati gbogbo àwọn ará Juda, lọ́mọdé ati lágbà, tọ wolii Jeremaya lọ. Wọ́n wí fún un pé, “Nǹkan kan ni a fẹ́ bẹ̀ ọ́ fún, a sì fẹ́ kí o ṣe é fún wa: jọ̀wọ́, gbadura sí OLUWA Ọlọrun rẹ fún àwa ati gbogbo àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù, nítorí pé a ti pọ̀ tẹ́lẹ̀ rí, ṣugbọn díẹ̀ ninu wa ni ó kù, bí ìwọ náà ti fi ojú ara rẹ rí i. A fẹ́ kí OLUWA Ọlọrun rẹ lè fi ọ̀nà tí a óo gbà hàn wá, kí ó sọ ohun tí a óo ṣe fún wa.” Wolii Jeremaya bá dá wọn lóhùn pé, “Mo gbọ́, n óo gbadura sí OLUWA Ọlọrun yín bí ẹ ti wí; gbogbo ìdáhùn tí OLUWA bá fún mi ni n óo sọ fun yín, n kò ní fi nǹkankan pamọ́.” Wọ́n wí fún Jeremaya pé, “Kí OLUWA ṣe ẹlẹ́rìí òtítọ́ ati òdodo bí a kò bá ṣe gbogbo nǹkan tí OLUWA Ọlọrun bá ní kí o sọ fún wa. Ìbáà jẹ́ rere ni OLUWA Ọlọrun wa tí a rán ọ sí sọ, kì báà jẹ́ burúkú, a óo gbọ́ràn sí i lẹ́nu; kí ó lè dára fún wa; nítorí pé ti OLUWA Ọlọrun wa ni a óo gbọ́.” Lẹ́yìn ọjọ́ kẹwaa, OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀. Jeremaya bá pe Johanani, ọmọ Karea ati gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, ati gbogbo àwọn eniyan, ati àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan pataki pataki. Ó sọ fún wọn pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, ẹni tí ẹ ní kí n gbé ẹ̀bẹ̀ yín lọ siwaju rẹ̀ ní, ‘Bí ẹ bá dúró ní ilẹ̀ yìí, n óo kọ yín bí ilé, n kò sì ní wo yín lulẹ̀. N óo gbìn yín bí igi, n kò sì ní fà yín tu, nítorí mo ti yí ọkàn mi pada nípa ibi tí mo ṣe sí yín. Ẹ má bẹ̀rù ọba Babiloni tí ẹrù rẹ̀ ń bà yín, ẹ má bẹ̀rù rẹ̀; èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, nítorí pé mo wà pẹlu yín. N óo gbà yín là n óo sì yọ yín lọ́wọ́ rẹ̀. N óo ṣàánú yín, n óo jẹ́ kí ó ṣàánú yín, kí ó sì jẹ́ kí ẹ máa gbé orí ilẹ̀ yín.’ “Bí ẹ bá wí pé ẹ kò ní dúró ní ilẹ̀ yìí, tí ẹ kò sì gbọ́ràn sí OLUWA Ọlọrun yín lẹ́nu; bí ẹ bá ń wí pé, ‘Rárá o, a óo sá lọ sí ilẹ̀ Ijipti, níbi tí a kò ti ní gbúròó ogun tabi fèrè ogun, níbi tí ebi kò ti ní pa wá, a óo sì máa gbé ibẹ̀,’ ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ̀yin tí ẹ ṣẹ́kù ní Juda. OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, ‘Bí ẹ bá gbójú lé àtilọ sí Ijipti, pé ẹ óo lọ máa gbé ibẹ̀, ogun tí ẹ̀ ń sá fún yóo bá yín níbẹ̀; ìyàn tí ẹ̀ ń bẹ̀rù yóo tẹ̀lé yín lọ sí Ijipti; ebi tí ẹ páyà rẹ̀ yóo gbá tẹ̀lé yín, ibẹ̀ ni ẹ óo sì kú sí. Gbogbo àwọn tí wọ́n bá gbójú lé àtilọ sí Ijipti láti máa gbé ibẹ̀ yóo kú ikú ogun, ati ti ìyàn pẹlu àjàkálẹ̀ àrùn, wọn kò ní ṣẹ́kù, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni wọn kò ní bọ́ ninu ibi tí n óo mú wá sórí wọn.’ “Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, ‘Bí mo ti bínú sí àwọn ará Jerusalẹmu, tí inú mi sì ń ru sí wọn, bẹ́ẹ̀ ni n óo bínú si yín nígbà tí ẹ bá dé Ijipti. Ẹ óo di ẹni ègún, ẹni àríbẹ̀rù, ẹni ẹ̀gàn ati ẹni ẹ̀sín. Ẹ kò sì ní fojú kan ilẹ̀ yìí mọ́.’ “OLUWA ti sọ fún ẹ̀yin tí ẹ ṣẹ́kù ní Juda pé kí ẹ má lọ sí Ijipti. Ẹ mọ̀ dájúdájú pé mo kìlọ̀ fun yín lónìí pé ẹ ti fi ẹ̀mí ara yín wéwu nítorí ìṣìnà yín. Nítorí pé nígbà tí ẹ rán mi sí OLUWA Ọlọrun yín pé kí n gbadura fun yín, gbogbo ohun tí OLUWA Ọlọrun yín bá wí ni kí n sọ fun yín, ẹ ní ẹ óo sì ṣe é. Mo ti sọ ohun tí Ọlọrun wí fun yín lónìí, ṣugbọn ẹ kò tẹ̀lé ọ̀kan kan ninu ohun tí OLUWA Ọlọrun yín ní kí n sọ fun yín. Nítorí náà ẹ mọ̀ dájú pé ẹ óo kú ikú ogun, ati ti ìyàn pẹlu àjàkálẹ̀ àrùn, ní ibi tí ẹ fẹ́ lọ máa gbé.” Nígbà tí Jeremaya parí gbogbo ọ̀rọ̀ tí OLUWA Ọlọrun wọn rán an sí gbogbo àwọn ará ìlú, Asaraya, ọmọ Hoṣaaya, ati Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo àwọn ọkunrin aláfojúdi kan wí fún Jeremaya pé, “Irọ́ ni ò ń pa. OLUWA Ọlọrun wa kò rán ọ láti sọ fún wa pé kí á má lọ ṣe àtìpó ní Ijipti. Baruku, ọmọ Neraya, ni ó fẹ́ mú wa kọlù ọ́, kí o lè fà wá lé àwọn ará Kalidea lọ́wọ́, kí wọ́n lè pa wá; tabi kí wọ́n kó wa lọ sí ìgbèkùn ní Babiloni.” Nítorí náà Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo àwọn olórí ogun ati gbogbo àwọn ará ìlú kò gba ohun tí OLUWA sọ, pé kí wọ́n dúró ní ilẹ̀ Juda. Kàkà bẹ́ẹ̀, Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo àwọn olórí ogun kó gbogbo àwọn ará Juda tí wọ́n ṣẹ́kù, tí wọ́n pada wá sí ilẹ̀ Juda láti oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti sálọ: àwọn ọkunrin ati àwọn obinrin, àwọn ọmọde, àwọn ìjòyè, ati gbogbo àwọn tí Nebusaradani, olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba Babiloni, fi sábẹ́ àkóso Gedalaya ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ati Jeremaya wolii ati Baruku ọmọ Neraya. Wọ́n kó wọn lọ sí ilẹ̀ Ijipti, nítorí wọn kò fetí sí ọ̀rọ̀ OLUWA Ọlọrun wọn. Wọ́n lọ títí tí wọ́n fi dé Tapanhesi. OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀ ní Tapanhesi: Ó ní, “Gbé òkúta ńláńlá lọ́wọ́, kí o bò wọ́n mọ́lẹ̀, níbi pèpéle tí ó wà lẹ́nu ọ̀nà ààfin Farao ní Tapanhesi, lójú àwọn ará Juda, kí o sì wí fún wọn pé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní òun óo lọ mú Nebukadinesari ọba Babiloni, iranṣẹ òun wá, yóo sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ ka orí àwọn òkúta tí òun rì mọ́lẹ̀ yìí, Nebukadinesari yóo sì tẹ́ ìtẹ́ ọlá rẹ̀ sórí wọn. Yóo wá kọlu ilẹ̀ Ijipti, yóo jẹ́ kí àjàkálẹ̀ àrùn pa àwọn tí yóo kú ikú àjàkálẹ̀ àrùn, yóo kó àwọn tí yóo lọ sí ìgbèkùn lọ sí ìgbèkùn, yóo sì fi idà pa àwọn tí yóo kú ikú idà. Yóo dáná sun àwọn ilé àwọn oriṣa ilẹ̀ Ijipti; yóo jó wọn níná; yóo sì kó àwọn ará ìlú lọ sí ìgbèkùn; yóo fọ ilẹ̀ Ijipti mọ́ bí darandaran tíí ṣa eégbọn kúrò lára aṣọ rẹ̀, yóo sì jáde kúrò níbẹ̀ ní alaafia. Yóo fọ́ àwọn òpó ilé oriṣa Heliopolisi tí ó wà ní ilẹ̀ Ijipti, yóo sì dáná sun àwọn ilé àwọn oriṣa ilẹ̀ Ijipti.” Nǹkan tí Jeremaya gbọ́ nípa gbogbo àwọn Juu tí wọn ń gbé Migidoli ati Tapanhesi, ati Memfisi ati ilẹ̀ Patirosi ní ilẹ̀ Ijipti nìyí. OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, “Ẹ rí gbogbo ibi tí mo jẹ́ kí ó bá Jerusalẹmu ati gbogbo ìlú Juda. Ẹ wò wọ́n lónìí bí wọ́n ti di ahoro, tí kò sì sí eniyan ninu wọn, nítorí ibi tí wọ́n ṣe, wọ́n mú mi bínú nítorí pé wọ́n sun turari sí àwọn oriṣa tí àwọn tabi àwọn baba wọn kò mọ̀ rí, wọ́n sì ń sìn wọ́n. Sibẹsibẹ mo rán gbogbo àwọn iranṣẹ mi, àwọn wolii, sí wọn, kí wọ́n sọ fún wọn pé kí wọn má ṣe ohun ìríra tí n kò fẹ́. Ṣugbọn wọn kò gbọ́ràn, wọn kò fetí sílẹ̀, wọn kò dáwọ́ ibi ṣíṣe dúró, wọn kò sì yé sun turari sí oriṣa mọ́. Mo bá bínú gan-an sí àwọn ìlú Juda ati ìgboro Jerusalẹmu; mo sì sọ wọ́n di aṣálẹ̀ ati ahoro bí wọ́n ti wà lónìí. “Èmi, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli wá ń bi yín léèrè pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe ara yín ní ibi tó báyìí? Ṣé ẹ fẹ́ kó gbogbo àwọn eniyan wọnyi kúrò ní ilẹ̀ Juda, ati àwọn ọkunrin ati àwọn obinrin, àtọmọ ọmú, àtọmọ ọwọ́, títí tí kò fi ní ku ẹnikẹ́ni ninu yín lẹ́yìn ni? Kí ló dé tí ẹ fi ń fi iṣẹ́ ọwọ́ yín bí mi ninu, tí ẹ̀ ń sun turari sí àwọn oriṣa ní ilẹ̀ Ijipti, níbi tí ẹ̀ ń gbé? Ṣé ẹ fẹ́ kí n pa yín run, kí ẹ di ẹni ẹ̀sín láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ni ẹ ṣe ń ṣe báyìí? Ṣé ẹ ti gbàgbé ibi tí àwọn baba ńlá yín ṣe ní ilẹ̀ Juda ati ìgboro Jerusalẹmu, tí àwọn ọba Juda ati àwọn ayaba ṣe ati ẹ̀yin pẹlu àwọn iyawo yín? Wọn kò rẹ ara wọn sílẹ̀ títí di òní, tabi kí wọn bẹ̀rù, tabi kí wọ́n pa òfin ati ìlànà tí mo fún ẹ̀yin ati àwọn baba yín mọ́.’ “Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, ‘Ẹ wò ó, n óo dójúlé yín, n óo sì pa gbogbo ọmọ Juda run. N óo run gbogbo àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ní ilẹ̀ Juda tí wọ́n gbójú lé àtilọ máa gbé ilẹ̀ Ijipti, wọn kò ní ku ẹyọ kan ní ilẹ̀ Ijipti. Gbogbo wọn ni wọn óo parun láti orí àwọn mẹ̀kúnnù dé orí àwọn eniyan pataki pataki; ogun ati ìyàn ni yóo pa wọ́n. Wọn yóo di ẹni ìfibú, ẹni àríbẹ̀rù, ẹni ègún ati ẹni ẹ̀sín. N óo fìyà jẹ àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ Ijipti, n óo fi ogun, ìyàn, ati àjàkálẹ̀ àrùn pa wọ́n run bí mo ṣe fi pa Jerusalẹmu run. Ẹnikẹ́ni kò ní yè ninu àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ní Juda, tí wọ́n lọ fi ilẹ̀ Ijipti ṣe ilé; wọn kò ní sá àsálà, wọn kò sì ní yè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní pada sí ilẹ̀ Juda tí ọkàn wọn fẹ́ pada sí. Wọn kò ní pada, àfi àwọn bíi mélòó kan ni wọ́n óo sá àsálà.’ ” Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n mọ̀ pé àwọn iyawo wọn ń sun turari sí àwọn oriṣa ati àwọn obinrin tí wọ́n pọ̀ gbáà tí wọn wà nítòsí ibẹ̀, ati àwọn tí wọn ń gbé Patirosi ní ilẹ̀ Ijipti, wọ́n bá dá Jeremaya lóhùn, wọ́n ní, “A kò ní fetí sì ọ̀rọ̀ tí ò ń bá wa sọ lórúkọ OLUWA. Ṣugbọn a óo máa san gbogbo ẹ̀jẹ́ wa, a óo máa sun turari sí ọbabinrin ojú ọ̀run, oriṣa wa, a óo sì máa ta ohun mímu sílẹ̀, bí àwa ati àwọn baba ńlá wa, ati àwọn ọba wa ati àwọn olórí wa ti ṣe ní gbogbo ìlú Juda ati ní ìgboro Jerusalẹmu; nítorí pé nígbà náà à ń jẹ oúnjẹ ní àjẹyó, ó dára fún wa, ojú wa kò sì rí ibi. Ṣugbọn láti ìgbà tí a ti dáwọ́ ati máa sun turari sí ọbabinrin ojú ọ̀run dúró, tí a kò sì máa ta ohun mímu sílẹ̀ mọ́, ni a kò ti ní nǹkankan mọ́, tí ogun ati ìyàn sì fẹ́ẹ̀ pa wá tán.” Àwọn obinrin bá tún dáhùn pé, “Nígbà tí à ń sun turari sí ọbabinrin ojú ọ̀run, tí a sì ń rú ẹbọ ohun mímu sí i, ṣé àwọn ọkọ wa ni kò mọ̀ pé à ń ṣe àkàrà dídùn, tí à ń ṣe bí ère rẹ̀ fún un ni, ati pé à ń ta ohun mímu sílẹ̀ fún un?” Jeremaya sọ fún gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n dá a lóhùn, lọkunrin ati lobinrin pé: “Ṣebí OLUWA ranti turari tí ẹ̀yin ati àwọn baba yín, ati àwọn ọba yín, ati àwọn ìjòyè yín, ati gbogbo àwọn eniyan ilẹ̀ náà sun ninu àwọn ìlú Juda ati ní ìgboro Jerusalẹmu, ṣebí OLUWA ranti. OLUWA kò lè farada ìwà burúkú tí ẹ̀ ń hù, ati àwọn nǹkan ìríra tí ẹ̀ ń ṣe, nítorí náà, ni ilẹ̀ yín ṣe di ahoro ati aṣálẹ̀, ati ilẹ̀ tí a fi ń gégùn-ún, tí kò ní olùgbé, títí di òní. Ìdí tí èyí fi ṣẹlẹ̀ si yín ni pé ẹ sun turari, ẹ sì dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA. Ẹ kò fetí sí ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ kò pa òfin, ati ìlànà rẹ̀ mọ́.” Jeremaya dá gbogbo àwọn eniyan náà lóhùn, pataki jùlọ àwọn obinrin, ó ní, “Ẹ gbọ́ nǹkan tí OLUWA sọ, gbogbo ẹ̀yin ará Juda tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ Ijipti, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, ‘Ẹ̀yin ati àwọn iyawo yín ti fi ẹnu ara yín sọ, ẹ sì ti fi ọwọ́ ara yín mú ohun tí ẹ wí ṣẹ pé, “Dájúdájú a ti jẹ́jẹ̀ẹ́ sí oriṣa ọbabinrin ojú ọ̀run láti sun turari sí i, ati láti rú ẹbọ ohun mímu sí i.” ’ Kò burú, ẹ mú ẹ̀jẹ́ yín ṣẹ! Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí, gbogbo ẹ̀yin ará Juda tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ Ijipti: Ó ní, ‘Ẹ wò ó, mo ti fi orúkọ ńlá mi búra pé àwọn ará Juda tí wọ́n wà ní Ijipti kò ní fi orúkọ mi búra mọ́ pé “Bí OLUWA ti wà láàyè.” Mo dójúlé yín láti ṣe yín ní ibi. Ibi ni n óo ṣe yín, n kò ní ṣe yín ní oore. Gbogbo àwọn ará Juda tí wọ́n wà ní Ijipti ni ogun ati ìyàn yóo pa láìku ẹnìkan. Àwọn eniyan díẹ̀ ni wọn yóo sá àsálà kúrò ní ilẹ̀ Ijipti lọ sí ilẹ̀ Juda. Gbogbo àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù ní Juda, tí wọ́n lọ sí Ijipti yóo wá mọ ọ̀rọ̀ ẹni tí yóo ṣẹ, bóyá tèmi ni, tabi tiwọn. Èyí ni yóo jẹ́ àmì fun yín pé n óo jẹ yín níyà ní ilẹ̀ yìí, kí ẹ lè mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ibi tí mo sọ si yín yóo ṣẹ mọ yín lára, Èmi OLUWA ni mo sọ ọ́ pé n óo fi Farao Hofira ọba Ijipti lé ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́ ati àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí mo ti fi Sedekaya, ọba Juda lé ọwọ́ ọ̀tá rẹ̀, Nebukadinesari, ọba Babiloni, ẹni tí ó ń wá ọ̀nà láti pa á.’ ” Ọ̀rọ̀ tí Jeremaya wolii sọ fún Baruku ọmọ Neraya nìyí, ní ọdún kẹrin tí Jehoiakimu, ọmọ Josaya, jọba ní Juda. Baruku ń kọ ohun tí Jeremaya ń sọ sílẹ̀ bí Jeremaya tí ń sọ̀rọ̀. Ó ní: “OLUWA Ọlọrun Israẹli sọ fún ìwọ Baruku pé, ò ń sọ pé, o gbé, nítorí pé OLUWA ti fi ìbànújẹ́ kún ìrora rẹ; àárẹ̀ mú ọ nítorí ìkérora rẹ, o kò sì ní ìsinmi. “Èmi ń wó ohun tí mo kọ́ lulẹ̀, mo sì ń tu ohun tí mo gbìn, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ gbogbo ilẹ̀ náà rí. Ìwọ ń wá nǹkan ńlá fún ara tìrẹ? Má wá nǹkan ńlá fún ara rẹ. Wò ó, n óo mú kí ibi bá gbogbo eniyan, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀; ṣugbọn n óo jẹ́ kí o máa sá àsálà ní gbogbo ibi tí o bá ń lọ.” Ọ̀rọ̀ tí OLUWA bá Jeremaya wolii sọ nípa àwọn orílẹ̀-èdè nìyí. Ọ̀rọ̀ lórí Ijipti: Nípa àwọn ọmọ ogun Farao Neko, ọba Ijipti, tí wọ́n wà létí odò Yufurate ní Kakemiṣi, àwọn tí Nebukadinesari, ọba Babiloni, ṣẹgun ní ọdún kẹrin tí Jehoiakimu ọmọ Josaya jọba Juda. “Ọ̀gágun Ijipti pàṣẹ fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pé, ‘Ẹ tọ́jú asà ati apata, kí ẹ sì jáde sójú ogun! Ẹ̀yin ẹlẹ́ṣin, ẹ di ẹṣin yín ní gàárì, kí ẹ sì gùn wọ́n. Ẹ dúró ní ipò yín, pẹlu àṣíborí lórí yín. Ẹ pọ́n àwọn ọ̀kọ̀ yín, kí ẹ gbé ihamọra irin yín wọ̀!’ ” Oluwa ní, “Kí ni mo rí yìí? Ẹ̀rù ń bà wọ́n, wọ́n sì ń pada sẹ́yìn. A ti lu àwọn ọmọ ogun wọn bolẹ̀, wọ́n sì ń sálọ pẹlu ìkánjú; wọn kò bojú wẹ̀yìn, ìpayà yí wọn ká! Àwọn tí ẹsẹ̀ wọn yá nílẹ̀ kò lè sálọ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ogun kò lè sá àsálà. Ìhà àríwá, lẹ́bàá odò Yufurate, ni wọ́n tí fẹsẹ̀ kọ, tí wọ́n sì ṣubú. Ta ló ń ru bí odò Naili yìí, bí odò tí ó kún bo bèbè rẹ̀? Ijipti ń ru bí odò Naili, bí odò tí ó kún bo bèbè rẹ̀. Ijipti wí pé, ‘N óo kún, n óo sì bo ayé mọ́lẹ̀, n óo pa àwọn ìlú ati àwọn tí wọn ń gbé inú wọn run. Ó yá, ẹṣin, ẹ gbéra, kí kẹ̀kẹ́ ogun máa sáré kíkankíkan! Kí àwọn ọmọ ogun máa nìṣó, àwọn ọmọ ogun Etiopia ati Puti, tí wọ́n mọ asà á lò, àwọn ọmọ ogun Ludi, tí wọ́n mọ ọfà á ta dáradára.’ ” Ọjọ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ọjọ́ náà, ọjọ́ ẹ̀san, tí yóo gbẹ̀san ara rẹ̀ lára àwọn ọ̀tá rẹ̀. Idà rẹ̀ yóo pa àpatẹ́rùn, yóo sì mu ẹ̀jẹ̀ wọn ní àmuyó. Nítorí OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní ń rúbọ, ní ìhà àríwá, lẹ́bàá odò Yufurate. Gòkè lọ sí Gileadi, kí o lọ wá ìwọ̀ra, ẹ̀yin ará Ijipti, asán ni gbogbo òògùn tí ẹ lò, ẹ kò ní rí ìwòsàn. Àwọn orílẹ̀ èdè ti gbọ́ nípa ìtìjú yín, igbe yín ti gba ayé kan; nítorí àwọn ọmọ ogun ń rọ́ lu ara wọn; gbogbo wọn sì ṣubú papọ̀. Ohun tí OLUWA sọ fún wolii Jeremaya nípa Nebukadinesari, ọba Babiloni nígbà tí ó ń bọ̀ wá ṣẹgun ilẹ̀ Ijipti nìyí: Ó ní, “Ẹ kéde ní Ijipti, ẹ polongo ní Migidoli, ní Memfisi ati ní Tapanhesi. Ẹ wí pé, ‘Ẹ gbáradì kí ẹ sì múra sílẹ̀, nítorí ogun yóo run yín yíká. Kí ló dé tí àwọn akọni yín kò lè dúró? Wọn kò lè dúró nítorí pé OLUWA ni ó bì wọ́n ṣubú.’ Ogunlọ́gọ̀ yín ti fẹsẹ̀ kọ, wọ́n sì ṣubú, wọ́n wá ń wí fún ara wọn pé, ‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí á pada sọ́dọ̀ àwọn eniyan wa, ati sí ilẹ̀ tí wọn gbé bí wa, nítorí ogun àwọn aninilára.’ “Ẹ pa orúkọ Farao, ọba Ijipti dà, ẹ pè é ní, ‘Aláriwo tí máa ń fi anfaani rẹ̀ ṣòfò.’ Ọba, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun, fi ara rẹ̀ búra pé, bí òkè Tabori ti rí láàrin àwọn òkè, ati bí òkè Kamẹli létí òkun, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan tí yóo yọ si yín yóo rí. Ẹ di ẹrù yín láti lọ sí ìgbèkùn, ẹ̀yin ará Ijipti! Nítorí pé Memfisi yóo di òkítì àlàpà, yóo di ahoro, kò sì ní sí ẹni tí yóo máa gbé ibẹ̀. Ijipti dàbí ọmọ mààlúù tí ó lẹ́wà, ṣugbọn irù kan, tí ó ti ìhà àríwá fò wá, ti bà lé e. Àwọn ọmọ ogun tí ó fi owó bẹ̀ lọ́wẹ̀, dàbí akọ mààlúù àbọ́pa láàrin rẹ̀; àwọn náà pẹ̀yìndà, wọ́n ti jọ sálọ, wọn kò lè dúró; nítorí ọjọ́ ìdààmú wọn ti dé bá wọn, ọjọ́ ìjìyà wọn ti pé. Ó ń dún bí ejò tí ó ń sálọ; nítorí pé àwọn ọ̀tá rẹ̀ ń bọ̀ tagbára tagbára, wọ́n ń kó àáké bọ̀ wá bá a, bí àwọn tí wọn ń gé igi. Wọn yóo gé igi inú igbó rẹ̀ lulẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igbó náà dí, nítorí pé igi ibẹ̀ pọ̀ bí eṣú, tí wọn kò sì lóǹkà. A óo dójú ti àwọn ará Ijipti, a óo fà wọ́n lé àwọn ará ìhà àríwá lọ́wọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní: “N óo fi ìyà jẹ Amoni, oriṣa Tebesi, ati Farao, ati Ijipti pẹlu àwọn oriṣa rẹ̀, ati àwọn ọba rẹ̀. N óo fìyà jẹ Farao ati àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e. N óo fà wọ́n lé àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí wọn lọ́wọ́; n óo fà wọ́n fún Nebukadinesari, ọba Babiloni, ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀. Lẹ́yìn náà, àwọn eniyan yóo máa gbé Ijipti bíi ti àtijọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” “Ṣugbọn ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, iranṣẹ mi, ọmọ Israẹli, ẹ má fòyà; n óo gbà yín là láti ọ̀nà jíjìn, n óo kó arọmọdọmọ yín yọ ní ilẹ̀ ìgbèkùn. Ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, ẹ óo pada máa gbé ní ìrọ̀rùn. Kò sì ní sí ẹni tí yóo dẹ́rù bà yín. Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, iranṣẹ mi, nítorí pé mo wà pẹlu yín. N óo run gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí mo le yín lọ, ṣugbọn n kò ní pa yín run. Bí ó bá tọ́ kí n jẹ yín níyà, n óo jẹ yín níyà, kìí ṣe pé n óo fi yín sílẹ̀ láìjẹ yín níyà. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA bá Jeremaya wolii sọ̀rọ̀ nípa Filistini kí Farao tó ṣẹgun Gasa, Ó ní, “Wò ó, omi kan ń ru bọ̀ láti ìhà àríwá, yóo di àgbàrá tí ó lágbára; yóo ya bo ilẹ̀ yìí ati gbogbo ohun tí ó wà lórí rẹ̀, yóo ya bo ìlú yìí pẹlu, ati àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀. Àwọn eniyan yóo kígbe: gbogbo àwọn ará ìlú yóo sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn. Nígbà tí pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin bá ń dún, tí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ bá ń sáré, tí ẹsẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́ ogun sì ń pariwo, Àwọn baba kò ní lè wo àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn pé kí àwọn fà wọ́n, nítorí pé ọwọ́ wọn yóo rọ; nítorí ọjọ́ tí ń bọ̀, tí yóo jẹ́ ọjọ́ ìparun gbogbo àwọn ará Filistia, ọjọ́ tí a óo run gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ tí ó kù fún Tire ati Sidoni. Nítorí pé OLUWA yóo pa àwọn ará Filistia run, àwọn tí wọ́n kù ní etí òkun ní Kafitori. Ìbànújẹ́ ti dé bá Gasa, Aṣikeloni ti parun. Ẹ̀yin tí ẹ kù lára àwọn ọmọ Anakimu, ẹ óo ti fi ìbànújẹ́ ṣá ara yín lọ́gbẹ́ pẹ́ tó? Ẹ̀yin ń bèèrè pé, ‘Ìwọ idà OLUWA, yóo ti pẹ́ tó kí o tó sinmi? Pada sinu àkọ̀ rẹ, máa sinmi kí o sì dúró jẹ́ẹ́.’ Ṣugbọn idà OLUWA ṣe lè dákẹ́ jẹ́ẹ́, nígbà tí Oluwa fún un ní iṣẹ́ láti ṣe? OLUWA ti pàṣẹ fún un láti kọlu Aṣikeloni, ati àwọn ìlú etí òkun.” OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli sọ nípa Moabu pé, “Nebo gbé nítorí yóo di ahoro! Ojú yóo ti Kiriataimu nítorí ogun óo kó o; ìtìjú yóo bá ibi ààbò rẹ̀, wọn óo wó o lulẹ̀; ògo Moabu ti dópin! Wọ́n ń pète ibi sí i ní Heṣiboni, wọ́n ní, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ pa á run, kí ó má jẹ́ orílẹ̀-èdè mọ́!’ Ẹ̀yin ará Madimeni pàápàá, kẹ́kẹ́ yóo pa mọ yín lẹ́nu; ogun yóo máa le yín kiri. Gbọ́ igbe kan ní Horonaimu, igbe ìsọdahoro ati ìparun ńlá! “Moabu ti parun; a gbọ́ igbe àwọn ọmọ rẹ̀. Bí wọn tí ń gun òkè Luhiti, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń sọkún, nítorí pé nígbà tí wọn tí ń lọ níbi ẹsẹ̀ òkè Horonaimu, ni wọ́n tí ń gbọ́ igbe ìparun; pé, ‘Ẹ sá! Ẹ sá àsálà fún ẹ̀mí yín! Ẹ sáré bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aṣálẹ̀!’ “Ọwọ́ yóo tẹ ìwọ náà, Moabu, nítorí pé o gbójú lé ibi ààbò ati ọrọ̀ rẹ. Oriṣa Kemoṣi yóo lọ sí ìgbèkùn, pẹlu àwọn babalóòṣà ati àwọn ìjòyè rẹ̀. Apanirun yóo wọ gbogbo ìlú, ìlú kankan kò sì ní bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀; àwọn àfonífojì yóo pòórá, a óo sì pa àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ run. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Ẹ bá Moabu wá ìyẹ́, nítorí yóo fò bí ẹyẹ; àwọn ìlú rẹ̀ yóo di ahoro, kò ní ku ẹnikẹ́ni ninu wọn.” (Ègún ń bẹ lórí ẹni tí ó bá ń fi ìmẹ́lẹ́ ṣe iṣẹ́ OLUWA; ègún sì ń bẹ lórí ẹni tí ó bá sì kọ̀, tí kò máa fi idà rẹ̀ pa eniyan.) OLUWA ní, “Láti ìgbà èwe Moabu ni ó ti ń gbé pẹlu ìrọ̀rùn, kò tíì lọ sí ìgbèkùn rí. Nítorí náà ó silẹ̀ bí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ ọtí. A kò máa dà á kiri láti inú ìgò kan sí òmíràn. Adùn rẹ̀ ṣì wà lára rẹ̀, òórùn rẹ̀ kò sì tíì yipada. “Nítorí náà, àkókò ń bọ̀, tí n óo jẹ́ kí wọn da Moabu nù, bí ẹni da ọtí nù. Àwọn tí wọn ń da ọtí nù ni n óo rán, tí wọn óo wá tẹ̀ ẹ́ bí ìgò ọtí wọn óo dà á nù patapata, wọn óo sì fọ́ ìgò rẹ̀. Kemoṣi yóo di ohun ìtìjú fún Moabu, gẹ́gẹ́ bí Bẹtẹli, tí Israẹli gbójú lé, ṣe di ohun ìtìjú fún Israẹli. Ẹ ṣe lè wí pé alágbára ni yín, ati pé ẹ jẹ́ akikanju lójú ogun? Ẹni tí yóo pa ilẹ̀ Moabu ati àwọn ìlú rẹ̀ run ti dé, àwọn àṣàyàn ọmọkunrin rẹ̀ sì ti lọ sí ibi tí wọn ó ti pa wọ́n. Èmi ọba, tí orúkọ mi ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun, ni ó sọ bẹ́ẹ̀. Ọjọ́ ìdààmú Moabu fẹ́rẹ̀ dé, ìpọ́njú rẹ̀ sì ń bọ̀ kánkán. “Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ yí i ká, ẹ dárò rẹ̀, kí gbogbo ẹ̀yin tí ẹ mọ orúkọ rẹ̀ sì wí pé, ‘Ọ̀pá àṣẹ tí ó lágbára ti kán, ọ̀pá àṣẹ tí ó lógo ti ṣẹ́.’ Sọ̀kalẹ̀ kúrò ninu ògo rẹ, kí o jókòó lórí ìyàngbẹ ilẹ̀, ìwọ tí ò ń gbé Diboni! Nítorí pé ẹni tí óo pa Moabu run ti dojú kọ ọ́, ó sì ti wó àwọn ibi ààbò rẹ̀. Dúró lẹ́bàá ọ̀nà kí o máa ṣọ́nà, ìwọ tí ò ń gbé Aroeri! Bèèrè lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n sálọ; bi àwọn tí ń sá àsálà pé, ‘Kí ló ṣẹlẹ̀?’ Ìtìjú ti bá Moabu, nítorí pé ó ti wó lulẹ̀; ẹ kígbe, ẹ máa sọkún. Ẹ kéde rẹ̀ ní ipadò Anoni, pé, ‘Moabu ti parẹ́, ó ti di òkítì àlàpà.’ “Ìdájọ́ ti dé sórí àwọn ìlú tí ó wà ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú: Holoni, Jahisai, ati Mefaati; Diboni, Nebo, ati Beti Dibilataimu, Kiriataimu, Betigamuli, ati Betimeoni, Kerioti, Bosira, ati gbogbo àwọn ìlú ilẹ̀ Moabu, ati àwọn tí wọ́n wà nítòsí, ati àwọn tí wọ́n wà lókèèrè. Ipá Moabu ti pin, a sì ti ṣẹ́ ẹ lápá. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA ní, “Ẹ rọ Moabu lọ́tí yó, nítorí pé ó gbéraga sí OLUWA; kí ó lè máa yíràá ninu èébì rẹ̀, a óo sì fi òun náà ṣẹ̀sín. Moabu, ṣebí ò ń fi Israẹli ṣe yẹ̀yẹ́? Ṣé o bá a láàrin àwọn ọlọ́ṣà ni, tí ó fi jẹ́ pé nígbàkúùgbà tí o bá ń sọ̀rọ̀ rẹ̀, ń ṣe ni o máa ń mi orí rẹ? “Ẹ fi ààrin ìlú sílẹ̀, kí ẹ lọ máa gbé inú àpáta, ẹ̀yin ará Moabu! Ẹ ṣe bí àdàbà, tí ó kọ́lé rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ẹnu ihò àpáta. A ti gbọ́ nípa ìgbéraga Moabu, ó ní ìgbéraga lọpọlọpọ, a ti gbọ́ nípa èrò gíga rẹ̀, ati ìgbéraga rẹ̀, nípa àfojúdi rẹ̀, ati nípa ìwà ìjọra-ẹni-lójú rẹ̀. Mo mọ̀ pé aláfojúdi ni. Ó ń fọ́nnu lásán ni, kò lè ṣe nǹkankan tó yanjú. Nítorí náà, ni mo ṣe ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, tí mò ń kígbe sókè nítorí Moabu tí mo sì ń ṣọ̀fọ̀ nítorí àwọn ará Kiri Heresi. Ìwọ ọgbà àjàrà Sibima, ọ̀rọ̀ rẹ pa mí lẹ́kún, ju ti Jaseri lọ! Àwọn ẹ̀ka rẹ tàn dé òkun, wọ́n tàn títí dé Jaseri, apanirun sì ti kọlu àwọn èso ẹ̀ẹ̀rùn rẹ, ati èso àjàrà rẹ. Wọ́n ti mú ayọ̀ ati ìdùnnú kúrò ní ilẹ̀ ọlọ́ràá Moabu; mo ti mú kí ọtí waini tán níbi tí wọ́n ti ń ṣe é, kò sí ẹni tí ó ń ṣe ọtí waini pẹlu ariwo ayọ̀ mọ́, ariwo tí wọn ń pa kì í ṣe ti ayọ̀. “Heṣiboni ati Eleale kígbe sókè, igbe wọn sì dé Jahasi láti Soari, ó dé Horonaimu ati Egilati Ṣeliṣiya. Àwọn odò Nimrimu pàápàá ti gbẹ. N óo pa àwọn tí ń rú ẹbọ níbi pẹpẹ ìrúbọ run, ati àwọn tí ń sun turari sí oriṣa ní ilẹ̀ Moabu. “Nítorí náà ni mo ṣe ń dárò Moabu ati àwọn ará Kiri Heresi bí ẹni fi fèrè kọ orin arò nítorí pé gbogbo ọrọ̀ tí wọ́n kó jọ ti ṣègbé. Gbogbo wọn ti fá irun orí ati irùngbọ̀n wọn; wọ́n ti fi abẹ ya gbogbo ọwọ́ wọn, wọ́n sì lọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ìbàdí. Gbogbo eniyan ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn ní gbogbo orí ilé Moabu, ati àwọn ìta gbangba rẹ̀. Nítorí pé mo ti fọ́ Moabu, bíi ohun èlò tí ẹnikẹ́ni kò bìkítà fún. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. A ti fọ́ Moabu túútúú! Ẹ̀ ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn! Moabu pẹ̀yìndà pẹlu ìtìjú! Moabu wá di ẹni yẹ̀yẹ́ ati ẹni àríbẹ̀rù fún gbogbo àwọn tí wọ́n yí i ká.” OLUWA ní, “Wò ó, ẹnìkan yóo fò wá bí ẹyẹ idì, yóo sì na ìyẹ́ apá rẹ̀ lé Moabu lórí. Ogun yóo kó àwọn ìlú Moabu, wọn óo sì gba àwọn ibi ààbò rẹ̀. Ní ọjọ́ náà, ọkàn àwọn ọmọ ogun Moabu yóo dàbí ọkàn obinrin tí ó ń rọbí, Moabu yóo parun, kò ní jẹ́ orílẹ̀-èdè mọ́, nítorí pé ó ṣe ìgbéraga sí OLÚWA. Ẹ̀yin ará Moabu, ìpayà, ọ̀gbun ati tàkúté ń bẹ níwájú yín! Ẹni tí ó ń sálọ nítorí ìpayà, yóo jìn sinu ọ̀gbun, ẹni tí ó bá sì jáde ninu ọ̀gbun yóo kó sinu tàkúté. N óo mú kí àwọn nǹkan wọnyi dé bá Moabu nígbà tí àkókò ìjìyà rẹ̀ bá tó. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Àwọn tí wọn ń sá fún ogun dúró ní ibi ààbò Heṣiboni, wọn kò lágbára mọ́, nítorí iná ṣẹ́ jáde láti Heṣiboni ahọ́n iná sì yọ láàrin ilé Sihoni ọba; iná ti jó Moabu tíí ṣe adé àwọn ọmọ onídàrúdàpọ̀ ní àjórun, Ẹ̀yin ará Moabu, ẹ gbé! Ó ti parí fun yín, ẹ̀yin ọmọ Kemoṣi, nítorí a ti kó àwọn ọmọkunrin yín lẹ́rú, a ti kó àwọn ọmọbinrin yín lọ sí ìgbèkùn. “Sibẹsibẹ n óo dá ire Moabu pada lẹ́yìn ọ̀la, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún Moabu.” Ohun tí OLUWA sọ nípa àwọn ará Amoni nìyí: Ó ní, “Ṣé Israẹli kò lọ́mọ ni? Tabi kò ní àrólé? Kí ló dé tí àwọn tí ń bọ Milikomu ṣe gba ilẹ̀ ẹ̀yà Gadi, tí wọ́n sì fi àwọn ìlú Gadi ṣe ibùjókòó? Nítorí náà, wò ó, àkókò ń bọ̀ tí n óo jẹ́ kí ariwo ogun sọ, ní Raba ìlú àwọn ọmọ Amoni; Raba yóo di òkítì àlàpà, a óo sì dáná sun àwọn ìgbèríko rẹ̀; Israẹli yóo wá pada fi ogun kó àwọn tí wọ́n kó o lẹ́rú. Sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ìwọ Heṣiboni, nítorí pé ìlú Ai ti parun! Ẹ sọkún, ẹ̀yin ọmọbinrin Raba! Ẹ ró aṣọ ọ̀fọ̀, ẹ máa sọkún, kí ẹ sì máa sá sókè sódò láàrin ọgbà! Nítorí pé oriṣa Moleki yóo lọ sí ìgbèkùn, pẹlu àwọn babalóòṣà rẹ̀ ati àwọn ìjòyè ní ibi ìsìn rẹ̀. Kí ló dé tí ò ń fọ́nnu nípa agbára rẹ, ipá rẹ ti pin, ìwọ olóríkunkun ọmọbinrin ìwọ tí o gbójú lé ọrọ̀ rẹ, tí ò ń wí pé, ‘Ta ló lè dojú kọ mí?’ Wò ó! N óo kó ìpayà bá ọ, láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí wọ́n yí ọ ká; èmi OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Gbogbo yín ni yóo fọ́nká, tí olukuluku yóo sì yà sí ọ̀nà tirẹ̀, kò sì ní sí ẹni tí yóo kó àwọn tí ń sá fún ogun jọ. “Ṣugbọn lẹ́yìn náà, n óo dá ire àwọn ará Amoni pada. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” Ohun tí OLUWA àwọn ọmọ ogun sọ nípa Edomu nìyí: Ó ní, “Ṣé kò sí ọgbọ́n ní Temani mọ́ ni? Àbí àwọn amòye kò ní ìmọ̀ràn lẹ́nu mọ́? Ṣé ọgbọ́n ti rá mọ́ wọn ninu ni? Ẹ̀yin ará Dedani, ẹ pada kíá, ẹ máa sálọ. Ẹ wọ inú ihò lọ, kí ẹ lọ máa gbébẹ̀! Nítorí pé ní ìgbà tí mo bá jẹ ìran Esau níyà, n óo mú kí ibi dé bá wọn. Bí àwọn tí ń kórè èso àjàrà bá bẹ̀rẹ̀ sí kórè, ṣebí wọn a máa fi èso díẹ̀ díẹ̀ sílẹ̀? Bí àwọn olè bá wọlé lóru, ṣebí ìba ohun tí ó bá wù wọ́n ni wọn yóo kó? Ṣugbọn mo ti tú àwọn ọmọ Esau sí ìhòòhò, Mo ti sọ ibi tí wọn ń sápamọ́ sí di gbangba, wọn kò sì rí ibi sápamọ́ sí mọ́. Àwọn ọmọ wọn ti parun, pẹlu àwọn arakunrin wọn ati àwọn aládùúgbò wọn; àwọn pàápàá sì ti di àwátì. Fi àwọn ọmọ rẹ, aláìníbaba sílẹ̀, n óo pa wọ́n mọ́ láàyè, sì jẹ́ kí àwọn opó rẹ gbẹ́kẹ̀lé mi. “Bí àwọn tí kò yẹ kí wọ́n jìyà bá jìyà, ṣé ìwọ wá lè lọ láìjìyà? O kò ní lọ láìjìyà, dájúdájú ìyà óo jẹ ọ́. Nítorí pé mo ti fi ara mi búra, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, pé Bosira yóo di àríbẹ̀rù ati ohun ẹ̀gàn, ahoro ati ohun àmúgégùn-ún; àwọn ìlú rẹ̀ yóo sì di ahoro títí lae.” Mo ti gbọ́ ìròyìn láti ọ̀dọ̀ OLUWA, wọ́n ti rán ikọ̀ kan sí àwọn orílẹ̀-èdè, wọ́n ní kí wọn kéde pé, “OLUWA ní, ‘Ẹ kó ara yín jọ, kí ẹ kọlu Edomu, ẹ dìde, kí ẹ gbógun tì í! Nítorí pé n óo sọ ọ́ di kékeré láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, o óo sì di yẹpẹrẹ, láàrin àwọn ọmọ eniyan. Ẹ̀rù tí ó wà lára rẹ, ati ìgbéraga ọkàn rẹ ti tàn ọ́ jẹ, ìwọ tí ò ń gbé pàlàpálá àpáta, tí o fi góńgó orí òkè ṣe ibùgbé. Bí o tilẹ̀ kọ́ ìtẹ́ rẹ sí ibi gíga, bíi ti ẹyẹ idì, n óo fà ọ́ lulẹ̀ láti ibẹ̀. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ” OLUWA ní, “Edomu yóo sì di ibi àríbẹ̀rù, ẹ̀rù yóo máa ba gbogbo àwọn tí wọ́n bá gba ibẹ̀ kọjá, wọn yóo máa pòṣé nítorí ibi tí ó dé bá a. Yóo rí fún un bí ó ti rí fún Sodomu ati Gomora ati àwọn ìlú agbègbè wọn tí ó parun. Ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò ní dé sibẹ. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Wò ó, bí kinniun tií yọ ní aginjù odò Jọdani láti kọlu agbo aguntan, bẹ́ẹ̀ ni n óo yọ sí Edomu n óo sì mú kí ó sá kúrò lórí ilẹ̀ rẹ̀ lójijì. N óo sì yan ẹnikẹ́ni tí ó bá wù mí láti máa ṣe àkóso ibẹ̀; nítorí ta ló dàbí mi? Ta ló lè yẹ̀ mí lọ́wọ́ wò? Olùṣọ́-aguntan wo ló lè dúró dè mí? Nítorí náà, ẹ gbọ́ ète tí OLUWA pa lórí Edomu, ati èrò rẹ̀ lórí àwọn tí wọn ń gbé Temani. A óo kó agbo ẹran wọn lọ tọmọtọmọ, ibùjẹ àwọn ẹran wọn yóo parun nítorí tiwọn. Ariwo wíwó odi Edomu wọn yóo mi ilẹ̀ tìtì, a óo sì gbọ́ ìró rẹ̀ títí dé etí òkun pupa. Wò ó! Ẹnìkan yóo fò bí ẹyẹ idì, yóo na ìyẹ́ rẹ̀ sórí Bosira, ní ọjọ́ náà ọkàn àwọn ọmọ ogun Edomu yóo dàbí ọkàn obinrin tí ń rọbí.” Ohun tí OLUWA sọ nípa Damasku nìyí, Ó ní, “Ìdààmú dé bá Hamati ati Aripadi, nítorí pé wọ́n gbọ́ ìròyìn burúkú: Jìnnìjìnnì dà bò wọ́n, ọkàn wọn sì dàrú, bí omi òkun tí kò lè dákẹ́ jẹ́ẹ́. Àárẹ̀ mú Damasku, ó pẹ̀yìndà pé kí ó máa sálọ, ṣugbọn ìpayà mú un, ìrora ati ìbànújẹ́ sì dé bá a, bí obinrin tí ń rọbí. Ẹ wò ó bí ìlú olókìkí tí ó kún fún ayọ̀, ṣe di ibi ìkọ̀sílẹ̀! Àwọn ọdọmọkunrin Damasku yóo ṣubú ní gbàgede rẹ̀ ní ọjọ́ náà, gbogbo àwọn ọmọ ogun ibẹ̀ yóo sì parun ni; Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo dáná sun odi Damasku, yóo sì jó ibi ààbò Benhadadi.” OLUWA sọ nípa Kedari ati àwọn ìjọba Hasori tí Nebukadinesari ọba Babiloni ṣẹgun pé, “Ẹ dìde kí ẹ gbógun ti Kedari! Ẹ pa àwọn ará ìlà oòrùn run! Ogun yóo kó àgọ́ wọn ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn lọ, ati àwọn aṣọ àgọ́, ati ohun ìní wọn; Ọ̀tá yóo kó ràkúnmí wọn lọ, àwọn eniyan yóo máa kígbe sí wọn pé, ‘Ìpayà wà ní gbogbo àyíká.’ “Ẹ̀yin ará Hasori, ẹ sá, ẹ lọ jìnnà réré, kí ẹ sì máa gbé inú ọ̀gbun. Nítorí pé Nebukadinesari, ọba Babiloni ń pète ibi si yín, ó ti pinnu ibi si yín. Ó ní, ‘Ẹ dìde kí ẹ gbógun ti orílẹ̀-èdè tí ó wà ní alaafia, ati láìléwu, ìlú tí ó dá dúró tí kò sì ní ìlẹ̀kùn tabi ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn fún ààbò.’ “Àwọn ràkúnmí ati agbo ẹran wọn yóo di ìkógun. N óo fọ́n àwọn tí wọn ń gé ẹsẹ̀ irun wọn ká sí igun mẹrẹẹrin ayé, n óo sì mú kí ibi bá wọn láti gbogbo àyíká wọn. Hasori yóo di ibùgbé ajáko, yóo di ahoro títí laelae. Ẹnìkan kò ní gbé ibẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò ní dé sibẹ mọ́.” OLUWA àwọn ọmọ ogun bá Jeremaya wolii sọ nípa Elamu ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekaya, ọba Juda. Ó ní, “Wò ó! N óo pa àwọn tafàtafà Elamu, tí wọn jẹ́ orísun agbára wọn, n óo mú kí ẹ̀fúùfù mẹrin láti igun mẹrẹẹrin ojú ọ̀run kọlu Elamu; n óo sì fọ́n wọn ká sinu ẹ̀fúùfù náà, kò sì ní sí orílẹ̀-èdè kan tí àwọn ará Elamu kò ní fọ́n ká dé. N óo dẹ́rùbà wọ́n; níwájú àwọn ọ̀tá wọn, ati níwájú àwọn tí ń wá ọ̀nà ati pa wọ́n. N óo bínú sí wọn gan-an, n óo sì mú kí ibi dé bá wọn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo rán ogun tẹ̀lé wọn, títí n óo fi pa wọ́n tán. N óo tẹ́ ìtẹ́ mi kalẹ̀ ní Elamu, n óo sì pa ọba ati àwọn ìjòyè wọn. Ṣugbọn nígbẹ̀yìn, n óo dá ire Elamu pada. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA bá wolii Jeremaya sọ̀rọ̀ nípa Babiloni ní ilẹ̀ àwọn ará Kalidea pé: “Kéde láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, ta àsíá, kí o sì kéde. Má fi ohunkohun pamọ́; sọ pé, ‘Ogun tí kó Babiloni, ojú ti oriṣa Bẹli, oriṣa Merodaki wà ninu ìdààmú. Ojú ti àwọn ère rẹ̀, ìdààmú sì bá wọn.’ “Nítorí pé orílẹ̀-èdè kan láti ìhà àríwá ti gbógun tì í, yóo sọ ilẹ̀ rẹ̀ di ahoro, kò sì ní sí ẹni tí yóo gbé inú rẹ̀ mọ́, ati eniyan ati ẹranko, wọn óo sá kúrò níbẹ̀. “Nígbà tí àkókò bá tó, àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn ọmọ Juda, yóo jọ wá pẹlu ẹkún, wọn yóo máa wá OLUWA Ọlọrun wọn. Wọn yóo bèèrè ọ̀nà Sioni, wọn yóo kọjú sibẹ, wọn yóo sì wí pé: ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á darapọ̀ mọ́ OLUWA, kí á sì bá a dá majẹmu ayérayé, tí a kò ní gbàgbé mọ́ títí ayé.’ “Àwọn eniyan mi dàbí aguntan tí ó sọnù, àwọn olùṣọ́ wọn ti ṣì wọ́n lọ́nà. Wọ́n ń lọ síhìn-ín, sọ́hùn-ún lórí òkè, wọ́n ń ti orí òkè kéékèèké bọ́ sí orí òkè ńláńlá; wọ́n ti gbàgbé ọ̀nà agbo wọn. Gbogbo àwọn tí wọn rí wọn ń pa wọ́n jẹ, àwọn ọ̀tá wọn sì ń wí pé, ‘A kò ní ẹ̀bi kankan, nítorí pé wọ́n ti ṣẹ OLÚWA, tí ó jẹ́ ibùgbé òdodo wọn, ati ìrètí àwọn baba wọn.’ “Ẹ sá kúrò láàrin Babiloni, ẹ jáde kúrò ní ilẹ̀ àwọn ará Kalidea, bí òbúkọ tí ó ṣáájú agbo ẹran. Nítorí n óo rú ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè sókè, láti ìhà àríwá, n óo sì kó wọn wá, wọn óo wá dóti Babiloni, wọn yóo gbógun tì í. Ibẹ̀ ni ọwọ́ wọn yóo ti tẹ̀ ẹ́, tí wọn óo sì fogun kó o. Ọfà wọn dàbí akọni ọmọ ogun, tí kì í pada sílé lọ́wọ́ òfo. Ohun ìní àwọn ará Kalidea yóo di ìkógun; gbogbo àwọn tí wọn yóo kó wọn lẹ́rù ni yóo kó ẹrù ní àkótẹ́rùn, Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA ní, “Ẹ̀yin ará Babiloni, tí ẹ kó àwọn eniyan mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé inú yín dùn ẹ sì ń yọ̀, tí ẹ sì ń ṣe ojúkòkòrò, bí akọ mààlúù tí ń jẹko ninu pápá, tí ẹ sì ń yan bí akọ ẹṣin: Ojú yóo ti olú-ìlú yín lọpọlọpọ, a óo dójú ti ilẹ̀ ìbí yín. Wò ó! Yóo di èrò ẹ̀yìn láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, yóo di aṣálẹ̀ tí ó gbẹ. Nítorí ibinu gbígbóná OLUWA, ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀ mọ́; yóo di ahoro patapata; ẹnu yóo ya gbogbo ẹni tí ó bá gba Babiloni kọjá, wọn yóo sì máa pòṣé nítorí ìyà tí a fi jẹ ẹ́. “Ẹ gbógun ti Babiloni yíká, gbogbo ẹ̀yin tafàtafà. Ẹ máa ta á lọ́fà, ẹ má ṣẹ́ ọfà kankan kù, nítorí pé ó ti ṣẹ OLUWA. Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ yí i ká, ẹ hó bò ó, ó ti jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀. Àwọn ibi ààbò rẹ̀ ti wó, àwọn odi rẹ̀ sì ti wó lulẹ̀. Nítorí ẹ̀san OLUWA ni, ẹ gbẹ̀san lára rẹ̀; ẹ ṣe sí i bí òun náà ti ṣe sí àwọn ẹlòmíràn. Ẹ pa àwọn afunrugbin run ní Babiloni, ati àwọn tí ń lo dòjé ní ìgbà ìkórè. Olukuluku yóo pada sọ́dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀, yóo sì sá pada sí ilẹ̀ rẹ̀, nítorí idà àwọn aninilára.” OLUWA ní, “Israẹli dàbí aguntan tí àwọn kinniun ń lé kiri. Ọba Asiria ni ó kọ́kọ́ fi ṣe ẹran ìjẹ, ọba Babiloni sì ń wó àwọn egungun rẹ̀ tí ó kù. Nítorí náà èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli, ni mo sọ pé n óo jẹ ọba Babiloni ati ilẹ̀ rẹ̀ níyà, bí mo ṣe jẹ ọba Asiria níyà. N óo mú Israẹli pada sí ibùjẹ rẹ̀, yóo máa jẹ oúnjẹ tí ó bá hù lórí òkè Kamẹli ati ní agbègbè Baṣani, yóo sì tẹ́ ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn lórí òkè Efuraimu ati òkè Gileadi. OLUWA ní, Nígbà tí ó bá yá, tí àkókò bá tó, a óo wá ẹ̀ṣẹ̀ tì ní Israẹli ati Juda; nítorí pé n óo dáríjì àwọn tí mo bá ṣẹ́kù.” OLUWA ní, “Ẹ gbógun ti ilẹ̀ Merataimu, ati àwọn ará Pekodi. Ẹ pa wọ́n, kí ẹ sì run wọ́n patapata. Gbogbo nǹkan tí mo pàṣẹ fun yín ni kí ẹ ṣe. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. A gbọ́ ariwo ogun ati ìparun ńlá, ní ilẹ̀ náà. Ẹ wo bí a ti gé òòlù tó ti ń lu gbogbo ayé lulẹ̀, tí a sì fọ́ ọ! Ẹ wo bí Babiloni ti di ohun àríbẹ̀rù, láàrin àwọn orílẹ̀-èdè. Mo dẹ tàkúté sílẹ̀ fun yín, ẹ̀yin ará Babiloni: Tàkúté náà mu yín, ẹ kò sì mọ̀. Wọ́n ri yín, ọwọ́ sì tẹ̀ yín, nítorí pé ẹ yájú sí èmi OLUWA. Mo ti ṣí ìlẹ̀kùn ilé ìṣúra àwọn nǹkan ìjà yín, mo sì kó àwọn ohun ìjà ibinu yín jáde, nítorí èmi OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní iṣẹ́ kan láti ṣe ní ilẹ̀ àwọn ará Kalidea. Ẹ gbógun tì í ní gbogbo ọ̀nà, ẹ ṣí àká rẹ̀ sílẹ̀, ẹ kó o jọ bí òkítì ọkà, kí ẹ sì pa á run patapata, ẹ má dá ohunkohun sí ninu rẹ̀. Ẹ pa gbogbo akọ mààlúù rẹ̀, ẹ fà wọ́n lọ sí ibi tí wọ́n ti ń pa ẹran. Àwọn ará Babiloni gbé, nítorí ọjọ́ wọn ti pé, àní ọjọ́ ìjìyà wọn.” (Ẹ gbọ́ ariwo bí àwọn eniyan tí ń sá àsálà kúrò ní ilẹ̀ Babiloni, wá sí Sioni, láti wá ròyìn ìgbẹ̀san Ọlọrun wa, ẹ̀san tẹmpili rẹ̀ tí wọ́n wó lulẹ̀.) “Ẹ pe àwọn tafàtafà jọ, kí wọn dojú kọ Babiloni; kí gbogbo àwọn tí wọn ń tafà pàgọ́ yí i ká, kí wọn má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni sá àsálà. Ẹ san án fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ẹ ṣe sí i bí ó ti ṣe sí àwọn ẹlòmíràn; nítorí pé ó ṣe àfojúdi sí OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli. Nítorí náà àwọn ọdọmọkunrin rẹ̀, yóo kú ní gbàgede rẹ̀. Gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ní a óo parun ní ọjọ́ náà. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “Wò ó! Mo dojú kọ ọ́, ìwọ onigbeeraga yìí, nítorí pé ọjọ́ ti pé tí n óo jẹ ọ́ níyà. Èmi OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Agbéraga, o óo fẹsẹ̀ kọ, o óo sì ṣubú, kò ní sí ẹni tí yóo gbé ọ dìde. N óo dá iná kan ninu àwọn ìlú rẹ, iná náà yóo sì jó gbogbo àyíká rẹ.” OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “À ń ni àwọn ọmọ Israẹli lára, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọmọ Juda; gbogbo àwọn tí wọ́n kó wọn ní ìgbèkùn ni wọ́n wo ọwọ́ mọ́ wọn, wọn kò jẹ́ kí wọn lọ. Ṣugbọn alágbára ni Olùràpadà wọn, OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀. Dájúdájú, yóo jà fún wọn, kí ó lè fún ayé ní ìsinmi, ṣugbọn kí ìdààmú lè bá àwọn ará Babiloni.” OLUWA ní, “Idà ni yóo pa àwọn ará Kalidea, idà ni yóo pa àwọn ará Babiloni, ati àwọn ìjòyè wọn, ati àwọn amòye wọn! Idà ni yóo pa àwọn awoṣẹ́ wọn, kí wọ́n lè di òpè! Idà ni yóo pa àwọn ọmọ ogun wọn, kí wọ́n lè parẹ́! Idà ni yóo pa àwọn ẹṣin wọn, ati àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn, idà ni yóo pa gbogbo àwọn àjèjì ọmọ ogun tí wọ́n wà láàrin wọn, Kí wọ́n lè di obinrin! Idà ni yóo fọ́ àwọn ilé ìṣúra wọn, kí wọ́n lè di ìkógun! Ọ̀dá yóo dá ní ilẹ̀ wọn, kí àwọn odò wọn lè gbẹ! Nítorí pé ilẹ̀ tí ó kún fún ère ni, wọ́n sì kúndùn ìbọ̀rìṣà. “Nítorí náà àwọn ẹranko ìgbẹ́ ati ìkookò ni yóo máa gbé inú Babiloni, ẹyẹ ògòǹgò yóo máa gbé inú rẹ̀. Kò ní sí eniyan níbẹ̀, ẹnikẹ́ni kò ní gbé inú rẹ̀ mọ́ títí lae. Yóo dàbí ìgbà tí Ọlọrun pa Sodomu ati Gomora run, pẹlu àwọn ìlú tí ó yí wọn ká; nítorí náà ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni eniyan kò ní máa dé sibẹ. “Wò ó! Àwọn kan ń bọ̀ láti ìhà àríwá, orílẹ̀-èdè ńlá, ati ọpọlọpọ ọba, wọ́n ń gbára wọn jọ láti máa bọ̀ láti òkèèrè. Wọ́n kó ọrun ati ọ̀kọ̀ lọ́wọ́, ìkà ni wọ́n, wọn kò ní ojú àánú. Ìró wọn dàbí ìró rírú omi òkun; wọ́n gun ẹṣin, wọ́n tò bí àwọn ọmọ ogun. Wọ́n ń bọ̀ wá dojú kọ ọ́, ìwọ Babiloni! Nígbà tí ọba Babiloni gbọ́ ìró wọn, ọwọ́ rẹ̀ rọ, ìrora sì mú un bíi ti obinrin tí ń rọbí. “Wò ó! Bí kinniun tíí yọ ní aginjù odò Jọdani tíí kọlu agbo aguntan, bẹ́ẹ̀ ni n óo yọ sí àwọn ará Babiloni, n óo mú kí wọn sá kúrò lórí ilẹ̀ wọn lójijì; n óo sì yan ẹnikẹ́ni tí ó bá wù mí láti máa ṣe àkóso ibẹ̀. Nítorí ta ló dàbí mi? Ta ló lè yẹ̀ mí lọ́wọ́ wò? Olùṣọ́-aguntan wo ló lè dúró dè mí? Nítorí náà, ẹ gbọ́ ète tí èmi OLUWA pa lórí Babiloni, ati èrò mi lórí àwọn ará Kalidea: A óo kó agbo ẹran wọn lọ tọmọtọmọ; ibùjẹ ẹran wọn yóo sì parun nítorí tiwọn. Ariwo wíwó odi Babiloni yóo mi ilẹ̀ tìtì, a óo sì gbọ́ ìró rẹ̀ káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè.” OLUWA ní, “Wò ó! N óo gbé ẹ̀mí apanirun kan dìde sí Babiloni, ati sí àwọn ará Kalidea; n óo rán ìjì líle kan sí Babiloni, ìjì náà yóo fẹ́ ẹ dànù bí ìyàngbò ọkà yóo sì sọ ilẹ̀ rẹ̀ di ahoro, nígbà tí wọ́n bá gbógun tì í yípo, ní ọjọ́ ìpọ́njú. Kí tafàtafà má kẹ́ ọrun rẹ̀, kí ó má sì gbé ẹ̀wù irin rẹ̀ wọ̀. Má ṣe dá àwọn ọdọmọkunrin rẹ̀ sí, pa gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ run patapata. Kí wọ́n ṣubú, kí wọ́n sì kú ní ilẹ̀ Kalidea, kí wọ́n gún wọn ní àgúnyọ láàrin ìgboro. Nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ati Juda kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀; ṣugbọn ilẹ̀ Kalidea kún fún ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀, tí wọ́n dá sí Ẹni Mímọ́ Israẹli. Ẹ sá kúrò láàrin Babiloni, kí olukuluku sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀! Ẹ má parun nítorí ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ Babiloni; nítorí àkókò ẹ̀san OLUWA nìyí, yóo sì san ẹ̀san fún Babiloni. Ife wúrà ni Babiloni jẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, ó ń pa gbogbo ayé bí ọtí; àwọn orílẹ̀-èdè mu ninu ọtí rẹ̀, wọ́n sì ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n. Babiloni ṣubú lójijì, ó sì fọ́; ẹ sun ẹkún arò nítorí rẹ̀! Ẹ fi ìwọ̀ra pa á lára nítorí ìrora rẹ̀, bóyá ara rẹ̀ yóo yá. À bá wo Babiloni sàn, ṣugbọn a kò rí i wòsàn. Ẹ pa á tì, ẹ jẹ́ kí á lọ, kí olukuluku máa lọ sí ilẹ̀ rẹ̀; nítorí ẹjọ́ tí a dá a ti dé òkè ọ̀run, a sì ti gbé e sókè dé ojú ọ̀run.” OLUWA ti dá wa láre; ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á lọ ròyìn iṣẹ́ OLUWA Ọlọrun wa ní Sioni. Ẹ pọ́n ọfà yín! Ẹ gbé asà yín! Nítorí OLUWA ti ru ẹ̀mí àwọn ọba Media sókè, nítorí pé ó ti pinnu láti pa Babiloni run. Ẹ̀san OLUWA ni, ẹ̀san nítorí tẹmpili rẹ̀ tí wọ́n wó. Ẹ gbé àsíá kan sókè, ẹ gbé e ti odi Babiloni; ẹ ṣe ìsénà tí ó lágbára. Ẹ fi àwọn aṣọ́nà sí ipò wọn; ẹ dira fún àwọn kan, kí wọn sápamọ́, nítorí OLUWA ti pinnu, ó sì ti ṣe ohun tí ó sọ nípa àwọn ará Babiloni. Ìwọ Babiloni, tí odò yí ká, tí ìṣúra rẹ pọ̀ lọpọlọpọ, òpin ti dé bá ọ, okùn tí ó so ayé rẹ rọ̀ ti já. OLUWA àwọn ọmọ ogun ti fi ara rẹ̀ búra, pé òun yóo mú kí àwọn eniyan kún inú rẹ bí eṣú, wọn yóo sì kígbe ìṣẹ́gun lé ọ lórí. OLUWA ni ó fi agbára rẹ̀ dá ilé ayé, tí ó fi ìdí ayé múlẹ̀ pẹlu ìmọ̀ rẹ̀, ó sì fi òye rẹ̀ ta àwọn ọ̀run bí aṣọ. Nígbà tí ó bá sọ̀rọ̀, ojú ọ̀run yóo kún fún alagbalúgbú omi, ó sì ń mú ìkùukùu gòkè láti òpin ilẹ̀ ayé. Ó dá mànàmáná fún òjò, ó sì mú ìjì jáde láti inú ilé ìṣúra rẹ̀. Òmùgọ̀ ni gbogbo eniyan, wọn kò sì ní ìmọ̀, gbogbo alágbẹ̀dẹ wúrà sì gba ìtìjú lórí oriṣa tí wọn dà; nítorí pé irọ́ ni ère tí wọ́n rọ, wọn kò ní èémí. Asán ni wọ́n, wọ́n ń ṣini lọ́nà, píparun ni wọn yóo parun, ní ọjọ́ ìjìyà wọn. Ọlọrun ti Jakọbu kò dàbí àwọn wọnyi, nítorí pé òun ní ẹlẹ́dàá ohun gbogbo; ẹ̀yà Israẹli ni eniyan tirẹ̀, OLUWA àwọn ọmọ ogun sì ni orúkọ rẹ̀. OLUWA sọ fún Babiloni pé, “Ìwọ ni òòlù ati ohun ìjà mi: ìwọ ni mo fi wó àwọn orílẹ̀-èdè wómúwómú, ìwọ ni mo sì fi pa àwọn ìjọba run. Ìwọ ni mo fi lu ẹṣin ati ẹni tí ń gùn ún pa; ìwọ ni mo fi wó kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn tí ń bẹ ninu wọn. Ìwọ ni mo fi lu tọkunrin tobinrin pa, ìwọ ni mo fi lu tọmọde, tàgbà pa, ìwọ ni mo sì fi run àwọn ọdọmọkunrin ati ọdọmọbinrin. Ìwọ ni mo fi pa olùṣọ́-aguntan ati agbo ẹran rẹ̀ rẹ́, ìwọ ni mo fi run àgbẹ̀ ati àwọn alágbàro rẹ̀, ìwọ ni mo fi ṣẹ́ apá àwọn gomina ati ti àwọn olórí ogun.” OLUWA ní, “Níṣojú yín ni n óo fi san ẹ̀san fún Babiloni, ati gbogbo àwọn tí wọn ń gbé Kalidea, fún gbogbo ibi tí wọ́n ṣe sí Sioni; èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Wò ó! Mo lòdì sí ọ, ìwọ òkè ìparun, tí ò ń pa gbogbo ayé run. N óo gbá ọ mú, n óo tì ọ́ lulẹ̀ láti orí àpáta, n óo sì sọ ọ́ di òkè tí ó jóná. Wọn kò ní rí òkúta kan mú jáde ninu rẹ, tí eniyan lè fi ṣe òkúta igun ilé; tabi tí wọn lè fi ṣe ìpìlẹ̀ ilé, ń ṣe ni o óo wó lulẹ̀ títí ayé. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “Ẹ ta àsíá sórí ilẹ̀ ayé, ẹ fun fèrè ogun láàrin àwọn orílẹ̀-èdè; kí àwọn orílẹ̀-èdè múra láti gbógun tì í, ẹ sì pe àwọn ìjọba jọ láti dojú kọ ọ́; àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè bíi Ararati, Minni, ati Aṣikenasi. Ẹ yan balogun tí yóo gbógun tì í; ẹ kó ẹṣin wá, kí wọn pọ̀ bí eṣú. Kí àwọn orílẹ̀-èdè múra láti gbógun tì í, kí àwọn ọba ilẹ̀ Media múra, pẹlu àwọn gomina wọn, ati àwọn ẹmẹ̀wà wọn, ati gbogbo ilẹ̀ tí ó wà lábẹ́ wọn. Jìnnìjìnnì bo gbogbo ilẹ̀ náà, wọ́n wà ninu ìrora, nítorí pé OLUWA kò yí ìpinnu rẹ̀ lórí Babiloni pada, láti sọ ilẹ̀ náà di ahoro, láìsí ẹnìkan kan ninu rẹ̀ mọ́. Àwọn ọmọ ogun Babiloni ti ṣíwọ́ ogun jíjà, wọ́n wà ní ibi ààbò wọn; àárẹ̀ ti mú wọn, wọ́n sì ti di obinrin. Àwọn ilé inú rẹ̀ ti ń jóná, àwọn ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn bodè rẹ̀ sì ti ṣẹ́. Àwọn tí ń sáré ń pàdé ara wọn lọ́nà, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ikọ̀ ń pàdé ara wọn, bí wọ́n ti ń sáré lọ sọ fún ọba Babiloni pé ogun ti gba ìlú rẹ̀ patapata. Wọ́n ti gba ibi ìsọdá odò, wọ́n ti dáná sun àwọn ibi ààbò, ìbẹ̀rùbojo sì ti mú àwọn ọmọ ogun. Babiloni dàbí ibi ìpakà, tí a tẹ̀ mọ́lẹ̀ nígbà tí à ń pa ọkà. Láìpẹ́ ọ̀tá yóo dà á wó, yóo sì di àtẹ̀mọ́lẹ̀. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “Nebukadinesari ọba Babiloni ti run Jerusalẹmu, ó ti tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, ó ti sọ ọ́ di ohun èlò òfìfo, ó gbé e mì bí erinmi, ó ti kó gbogbo ohun àdídùn inú rẹ̀ jẹ ní àjẹrankùn, ó ti da ìyókù nù. Jẹ́ kí àwọn tí ń gbé Sioni wí pé, ‘Kí ibi tí àwọn ará Babiloni ṣe sí wa ati sí àwọn arakunrin wa dà lé wọn lórí.’ Kí àwọn ará Jerusalẹmu sì wí pé, ‘Ẹ̀jẹ̀ wa ń bẹ lórí àwọn ará ilẹ̀ Kalidea.’ ” Nítorí náà, OLUWA sọ fún àwọn ará Jerusalẹmu pé, “Ẹ wò ó, n óo gba ẹjọ́ yín rò, n óo sì ba yín gbẹ̀san. N óo jẹ́ kí omi òkun Babiloni gbẹ, n óo sì jẹ́ kí orísun odò rẹ̀ gbẹ. Babiloni yóo sì di òkítì àlàpà, ati ibùgbé ajáko, yóo di ibi àríbẹ̀rù ati àrípòṣé, láìsí ẹnìkan kan ninu rẹ̀. Gbogbo wọn yóo bú papọ̀ bíi kinniun, wọn yóo sì ké bí àwọn ọmọ kinniun. Nígbà tí ara wọn bá gbóná, n óo se àsè kan fún wọn. N óo rọ wọ́n lọ́tí yó, títí tí wọn óo fi máa yọ ayọ̀ ẹ̀sín, tí wọn óo sì sùn lọ títí ayé. Wọn óo sùn, wọn kò sì ní jí mọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo fà wọ́n lọ sí ibi tí wọn tí ń pa ẹran, bí ọ̀dọ́ aguntan, ati àgbò ati òbúkọ.” OLUWA ní, “Ẹ wò ó bí ogun ti kó Babiloni, Babiloni tí gbogbo ayé ń pọ́nlé! Ó wá di àríbẹ̀rù láàrin àwọn orílẹ̀-èdè! Òkun ti ru bo Babiloni mọ́lẹ̀. Ìgbì òkun ti bò ó mọ́lẹ̀. Àwọn ìlú rẹ̀ ti di àríbẹ̀rù, wọ́n ti di ilẹ̀ gbígbẹ ati aṣálẹ̀, ilẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbé mọ́, tí ọmọ eniyan kò sì gbà kọjá mọ́. N óo fìyà jẹ oriṣa Bẹli ní Babiloni, n óo jẹ́ kí ó pọ ohun tí ó gbé mì. Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́, odi Babiloni pàápàá yóo wó lulẹ̀. “Ẹ̀yin eniyan mi, ẹ jáde kúrò níbẹ̀! Kí olukuluku sá àsálà, kúrò lọ́wọ́ ibinu gbígbóná OLUWA! Ẹ mọ́kàn, ẹ má bẹ̀rù, nítorí ìròyìn tí ẹ̀ ń gbọ́ nípa ilẹ̀ náà, nígbà tí ẹ bá gbọ́ ìròyìn kan ní ọdún yìí, tí ẹ tún gbọ́ òmíràn ní ọdún tí ń bọ̀, tí ìwà ipá sì wà ní ilẹ̀ náà, tí àwọn ìjòyè sì ń dojú ìjà kọ ara wọn. Nítorí náà, wò ó, ọjọ́ ń bọ̀ tí n óo fìyà jẹ àwọn ère ilẹ̀ Babiloni. Ojú yóo ti gbogbo ilẹ̀ rẹ̀, òkú àwọn eniyan rẹ̀ tí ogun yóo pa, yóo wà nílẹ̀ káàkiri ìgboro. Nítorí náà, ọ̀run ati ayé, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn, yóo yọ̀ nítorí ìṣubú Babiloni, nítorí pé apanirun yóo wá gbógun tì í, láti ìhà àríwá, Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Bí àwọn tí ogun Babiloni pa ní àwọn orílẹ̀-èdè ayé, ti ṣubú níwájú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni Babiloni náà gbọdọ̀ ṣubú, nítorí àwọn tí wọ́n pa ní Israẹli.” OLUWA sọ fún àwọn eniyan rẹ̀ ní Babiloni pé, “Ẹ̀yin tí ẹ bọ́ lọ́wọ́ idà, ẹ má dúró, ẹ máa sálọ! Ẹ ranti OLUWA ní ilẹ̀ òkèèrè, kí ẹ sì máa ronú nípa Jerusalẹmu pẹlu. Ẹ̀ ń sọ pé ojú ń tì yín nítorí pé wọ́n kẹ́gàn yín; ẹ ní ìtìjú dà bò yín, nítorí pé àwọn àjèjì ti wọ ibi mímọ́ ilé OLUWA. Nítorí náà, èmi OLUWA ń sọ nisinsinyii pé, ọjọ́ ń bọ̀, tí n óo ṣe ìdájọ́ lórí àwọn ère rẹ̀; àwọn tí wọ́n fara gbọgbẹ́ yóo máa kérora, ní gbogbo ilẹ̀ rẹ̀. Bí Babiloni tilẹ̀ ga tí ó kan ojú ọ̀run, tí ó sì mọ odi yí àwọn ibi ààbò rẹ̀ gíga ká, sibẹsibẹ n óo rán apanirun sí i. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA ní, “Ẹ gbọ́ igbe kan láti Babiloni! Igbe ìparun ńlá láti ilẹ̀ àwọn ará Kalidea! Nítorí OLUWA ń wó Babiloni lulẹ̀, ó sì ń pa á lẹ́nu mọ́. Igbe wọn ta sókè bíi híhó omi òkun ńlá nítorí pé apanirun ti dé sí i, àní ó ti dé sí Babiloni. Ogun ti kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀, àwọn ọ̀tá ti rún àwọn ọfà rẹ̀ jégéjégé, nítorí pé Ọlọrun ẹ̀san ni èmi OLUWA, dájúdájú n óo gbẹ̀san. N óo jẹ́ kí àwọn ìjòyè rẹ̀ ati àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀ mu ọtí ní àmuyó, pẹlu àwọn gomina rẹ̀, àwọn ọ̀gágun rẹ̀, ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Wọn yóo sun oorun àsùnrayè, wọn kò sì ní jí mọ́ laelae. Bẹ́ẹ̀ ni èmi ọba, tí orúkọ mi ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun sọ. Odi Babiloni tí ó fẹ̀, yóo wó lulẹ̀, a óo sì dáná sun àwọn ẹnubodè rẹ̀ tí ó ga fíofío. Iṣẹ́ lásán ni àwọn eniyan ń ṣe, àwọn orílẹ̀-èdè sì ń yọ ara wọn lẹ́nu lásán ni, nítorí pé iná yóo jó gbogbo làálàá wọn.” Jeremaya wolii pa àṣẹ kan fún Seraaya, alabojuto ibùdó ogun, ọmọ Neraya, ọmọ Mahiseaya nígbà tí ó ń bá Sedekaya ọba Juda lọ sí Babiloni ní ọdún kẹrin ìjọba Sedekaya. Jeremaya kọ gbogbo nǹkan burúkú tí yóo ṣẹlẹ̀ sí Babiloni ati gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí ó sọ nípa rẹ̀ sinu ìwé kan. Ó bá pàṣẹ fún Seraaya pé nígbà tí ó bá dé Babiloni, kí ó rí i dájú pé ó ka gbogbo ohun tí òun kọ sinu ìwé náà sókè. Kí ó sọ pé, “OLUWA, o ti sọ pé o óo pa ibí yìí run, tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi ní sí nǹkankan tí yóo máa gbé inú rẹ̀ mọ́, ìbáà ṣe eniyan tabi ẹranko. O ní títí lae ni yóo di ahoro.” Jeremaya ní nígbà tí Seraaya bá ka ìwé yìí tán, kí ó di òkúta kan mọ́ ọn kí ó jù ú sí ààrin odò Yufurate, kí ó sì sọ wí pé, “Báyìí ni yóo rí fún Babiloni, kò sì ní gbérí mọ́, nítorí ibi tí OLUWA yóo mú kí ó dé bá a.” Ibí yìí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Jeremaya sọ parí sí. Ẹni ọdún mọkanlelogun ni Sedekaya nígbà tí ó jọba, ọdún mọkanla ni ó sì fi wà lórí oyè ní Jerusalẹmu. Hamutali, ọmọ Jeremaya ará Libina ni ìyá rẹ̀. Sedekaya ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, bí Jehoiakimu ti ṣe. Nǹkan tí ń ṣẹlẹ̀ ní Jerusalẹmu ati Juda burú débi pé inú fi bí OLUWA sí wọn tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi tì wọ́n jáde kúrò níwájú rẹ̀. Sedekaya ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Babiloni. Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù kẹwaa, ní ọdún kẹsan-an tí Sedekaya gorí oyè, Nebukadinesari, ọba Babiloni, dé sí Jerusalẹmu pẹlu gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Wọ́n dó tì í, wọ́n sì mọ òkítì sí ara odi rẹ̀ yíká. Wọ́n dóti ìlú náà títí di ọdún kọkanla ìjọba Sedekaya. Ní ọjọ́ kẹsan-an oṣù kẹrin, ìyàn mú ní ààrin ìlú tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ará ìlú kò fi rí oúnjẹ jẹ mọ́. Wọ́n lu odi ìlú, àwọn ọmọ ogun sì gba ibẹ̀ sá jáde lóru. Wọ́n gba ẹnu ọ̀nà tí ó wà láàrin àwọn odi meji tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọgbà ọba, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Kalidea yí ìlú náà po, wọ́n bá dorí kọ apá ọ̀nà àfonífojì odò Jọdani. Ṣugbọn àwọn ọmọ ogun Kalidea lépa ọba Sedekaya, wọ́n sì bá a ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹriko; gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ bá fọ́nká lẹ́yìn rẹ̀. Ọwọ́ àwọn ọmọ ogun Kalidea tẹ Sedekaya ọba, wọ́n sì mú un lọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni ní Ribila, ní ilẹ̀ Hamati, ọba Babiloni sì ṣe ìdájọ́ fún un. Ọba Babiloni pa àwọn ọmọ Sedekaya lójú rẹ̀, ó sì pa àwọn ìjòyè Juda ní Ribila. Ó yọ ojú Sedekaya mejeeji, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó mú un lọ sí Babiloni, ó sì jù ú sí ọgbà ẹ̀wọ̀n, títí tí ó fi kú. Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù karun-un, ní ọdún kọkandinlogun tí Nebukadinesari ọba Babiloni jọba, Nebusaradani, olórí àwọn tí ń ṣọ́ ọba Babiloni, wọ ìlú Jerusalẹmu. Ó sun ilé OLUWA níná ati ilé ọba ati gbogbo ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu; gbogbo àwọn ilé ńláńlá ní ó dáná sun. Gbogbo àwọn ọmọ ogun Kalidea tí wọ́n wà pẹlu olórí àwọn tí ń ṣọ́ Nebukadinesari ọba wó gbogbo odi Jerusalẹmu lulẹ̀ patapata. Nebusaradani, olórí àwọn olùṣọ́ ọba bá kó ninu àwọn talaka lẹ́rú pẹlu àwọn eniyan tí wọ́n kù ní ìlú, ati àwọn tí wọ́n ti sálọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni, ati àwọn oníṣẹ́-ọwọ́. Ṣugbọn ó ṣẹ́ àwọn díẹ̀ kù sílẹ̀ ninu àwọn talaka pé kí wọn máa ṣe ìtọ́jú ọgbà àjàrà kí wọn sì máa dá oko. Àwọn ọmọ ogun Kalidea fọ́ àwọn òpó bàbà tí ó wà ninu ilé OLUWA ati agbada omi tí ó wà níbẹ̀ pẹlu ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Gbogbo rẹ̀ ni wọ́n fọ́ tí wọn rún wómúwómú; wọ́n sì kó gbogbo bàbà tí ó wà ninu ilé OLUWA lọ sí Babiloni. Bákan náà ni wọ́n kó àwọn ìkòkò, ọkọ́, ati àwọn ọ̀pá tí wọn fi ń pa iná ẹnu àtùpà; àwọn àwokòtò, àwọn àwo turari, ati gbogbo àwọn ohun-èlò tí wọ́n fi bàbà ṣe, tí wọn ń lò fún ìsìn ninu ilé OLUWA. Wọ́n sì kó àwọn abọ́ kéékèèké, àwọn àwo ìfọnná, ati àwọn àwokòtò; àwọn ìkòkò, àwọn ọ̀pá fìtílà, ati àwọn àwo turari, ati àwọn abọ́ tí wọ́n fi ń ta ohun mímu sílẹ̀. Gbogbo nǹkan èlò tí wọ́n fi wúrà ati fadaka ṣe ni Nebusaradani, olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba Babiloni kó lọ. Bàbà tí Solomoni fi ṣe òpó mejeeji ati agbada omi, pẹlu àwọn mààlúù idẹ mejeejila tí wọ́n gbé agbada náà dúró, ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ tí Solomoni ọba ṣe fún ilé OLUWA kọjá wíwọ̀n. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn òpó náà ga ní igbọnwọ mejidinlogun, àyíká wọn jẹ́ igbọnwọ mejila, wọ́n nípọn, ní ìka mẹrin, wọ́n sì ní ihò ninu. Ọpọ́n idẹ orí rẹ̀ ga ní igbọnwọ marun-un, wọ́n ṣe ẹ̀wọ̀n bí ẹ̀gbà ọrùn ati èso Pomegiranate yí ọpọ́n náà ká. Òpó keji rí bákan náà pẹlu èso Pomegiranate. Mẹrindinlọgọrun-un ni àwọn èso Pomegiranate tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kọ̀ọ̀kan; ọgọrun-un ni gbogbo èso Pomegiranate tí ó wà ní àyíká ẹ̀wọ̀n náà. Olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba Babiloni mú Seraaya, olórí alufaa ati Sefanaya tí ó jẹ́ igbákejì rẹ̀ ati àwọn aṣọ́nà mẹtẹẹta. Ó sì mú ọ̀gágun tí ń ṣe àkóso àwọn ọmọ ogun, ati meje ninu àwọn aṣojú ọba tí wọn rí láàrin ìlú ati akọ̀wé olórí ogun tí ń kọ orúkọ àwọn eniyan sílẹ̀ fún ogun jíjà. Wọ́n tún kó ọgọta eniyan ninu àwọn ará ìlú tí wọn rí láàrin ìgboro. Nebusaradani olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba, kó wọn lọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni ní Ribila. Ọba Babiloni sì pa wọ́n ní Ribila ní ilẹ̀ Hamati. Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe kó àwọn eniyan Juda ní ìgbèkùn kúrò ní ilẹ̀ wọn. Iye àwọn eniyan tí Nebukadinesari kó lọ sí ìgbèkùn nìwọ̀nyí ní ọdún keje tí ó jọba, ó kó ẹgbẹẹdogun ó lé mẹtalelogun (3,023) lára àwọn Juu. Ní ọdún kejidinlogun, ó kó àwọn ẹgbẹrin ó lé mejilelọgbọn (832) eniyan ní Jerusalẹmu. Ní ọdún kẹtalelogun tí Nebukadinesari jọba, Nebusaradani, olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba, kó ojilelẹẹdẹgbẹrin ó lé marun-un (745) eniyan lára àwọn Juu. Gbogbo àwọn eniyan tí wọn kó lẹ́rú jẹ́ ẹgbaaji lé ẹgbẹta (4,600). Ní ọdún kẹtadinlogoji lẹ́yìn tí a ti mú Jehoiakini, ọba Juda lọ sí ìgbèkùn, ní ọjọ́ kẹẹdọgbọn oṣù kejila ọdún náà Efilimerodaki, ọba Babiloni yẹ ọ̀rọ̀ Jehoiakini wò ní ọdún tí ó gorí oyè, ó sì pàṣẹ pé kí á tú u sílẹ̀ kúrò ní àtìmọ́lé. Ó bá a sọ ọ̀rọ̀ rere, ó sì fi sí ipò tí ó ga jùlọ, àní ipò tí ó ga ju ti gbogbo àwọn ọba tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ní Babiloni lọ. Jehoiakini bọ́ aṣọ ẹ̀wọ̀n kúrò lọ́rùn, ó sì ń bá ọba jẹun lórí tabili ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. Ọba Babiloni sì rí i pé òun ń pèsè gbogbo ohun tí ó nílò lojoojumọ fún un títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. Ẹ wò ó bí ìlú tí ó kún fún eniyan tẹ́lẹ̀ ti di ahoro, tí ó wá dàbí opó! Ìlú tí ó tóbi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tẹ́lẹ̀! Tí ó sì dàbí ọmọ ọba obinrin láàrin àwọn ìlú yòókù. Ó ti wá di ẹni àmúsìn. Ó ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn lóru, omijé ń dà lójú rẹ̀, kò sì sí ẹni tí yóo tù ú ninu, láàrin àwọn alajọṣepọ rẹ̀. Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti dà á, wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì di ọ̀tá rẹ̀. Juda ti lọ sí ìgbèkùn, wọ́n sì ń fi tipátipá mú un sìn. Nisinsinyii, ó ń gbé ààrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, kò sì ní ibi ìsinmi. Ọwọ́ àwọn tí wọn ń lépa rẹ̀ ti tẹ̀ ẹ́, ninu ìdààmú rẹ̀. Àwọn ọ̀nà tó lọ sí Sioni ń ṣe ìdárò, nítorí kò sí ẹni tí ó ń gba ibẹ̀ lọ síbi àwọn àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀ mọ́. Àwọn ẹnubodè rẹ̀ ti di ahoro, àwọn alufaa rẹ̀ sì ń kẹ́dùn. Wọ́n ń pọ́n àwọn ọmọbinrin rẹ̀ lójú, òun pàápàá sì ń joró lọpọlọpọ. Àwọn ọ̀tá ilẹ̀ Juda ti borí rẹ̀, wọ́n ti wá di ọ̀gá rẹ̀, nítorí pé, OLUWA ń jẹ ẹ́ níyà fún ọpọlọpọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, àwọn ọ̀tá ti ti àwọn ọmọ rẹ̀ ṣáájú, wọ́n ti kó wọn nígbèkùn lọ. Gbogbo ògo Jerusalẹmu ti fò lọ kúrò lára rẹ̀, àwọn olórí rẹ̀ dàbí àgbọ̀nrín tí kò rí koríko tútù jẹ; agbára kò sí fún wọn mọ́, wọ́n ń sálọ níwájú àwọn tí ń lé wọn. Ní ọjọ́ ìpọ́njú ati ìbànújẹ́, Jerusalẹmu ranti àwọn nǹkan iyebíye tí ó ní ní ìgbà àtijọ́. Nígbà tí àwọn eniyan rẹ̀ bọ́ sọ́wọ́ ọ̀tá, tí kò sì sí ẹni tí yóo ràn wọ́n lọ́wọ́. Àwọn ọ̀tá bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ ọ́, wọ́n sì ń fi ṣẹ̀sín nítorí ìṣubú rẹ̀. Jerusalẹmu ti dẹ́ṣẹ̀ burúkú, nítorí náà ó ti di eléèérí. Àwọn tí wọn ń bu ọlá fún un tẹ́lẹ̀ ti ń kẹ́gàn rẹ̀, nítorí pé wọ́n ti rí ìhòòhò rẹ̀. Òun pàápàá ń kérora, ó sì fi ojú pamọ́. Ìwà èérí rẹ̀ hàn níbi ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, kò sì bìkítà fún ìparun tí ń bọ̀. Nítorí náà ni ìṣubú rẹ̀ fi pọ̀, tí kò sì fi ní olùtùnú. Ó ké pe OLUWA pé kí ó ṣíjú wo ìnira òun, nítorí pé ọ̀tá ti borí rẹ̀. Ọ̀tá ti tọwọ́ bọ ilé ìṣúra rẹ̀, wọ́n sì ti kó gbogbo nǹkan iyebíye inú rẹ̀ lọ; ó ń wo àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, tí wọn ń wọ ibi mímọ́ rẹ̀. Àwọn tí ó pàṣẹ pé wọn kò gbọdọ̀ dé àwùjọ àwọn eniyan rẹ̀. Gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ ń kérora bí wọ́n ti ń wá oúnjẹ; wọ́n ń fi ìṣúra wọn ṣe pàṣípààrọ̀ fún oúnjẹ kí wọ́n baà lè lágbára. Jerusalẹmu ń sunkún pé, “Bojúwò mí, OLUWA, nítorí pé mo di ẹni ẹ̀gàn.” Ó ní, “Ṣé ọ̀rọ̀ yìí kò kàn yín ni, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń kọjá lọ? Ẹ̀yin náà ẹ wò ó, kí ẹ ṣe akiyesi rẹ̀, bóyá ìbànújẹ́ kan wà tí ó dàbí èyí tí ó dé bá mi yìí; tí OLUWA mú kí ó dé bá mi, ní ọjọ́ ibinu gbígbóná rẹ̀. “Ó rán iná láti òkè ọ̀run wá; ó dá a sí egungun mi; ó dẹ àwọ̀n sílẹ̀ fún mi; ó sì dá mi pada. Mo dàbí odi, mo sì fi ìgbà gbogbo dákú. “Ó di ẹ̀ṣẹ̀ mi bí àjàgà, ó gbé e kọ́ mi lọ́rùn, ó sì sọ mí di aláìlágbára. OLUWA ti fi mí lé àwọn tí n kò lè dojú kọ lọ́wọ́. “OLUWA ti fi ẹsẹ̀ tẹ àwọn akọni mi mọ́lẹ̀; ó pe ọpọlọpọ eniyan jọ sí mi, ó ní kí wọ́n pa àwọn ọdọmọkunrin mi; OLUWA ti tẹ àwọn ọmọ Juda ní àtẹ̀rẹ́, bí ẹni tẹ èso àjàrà fún ọtí waini. “Nítorí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọnyi ni mo ṣe sọkún; tí omijé ń dà lójú mi; olùtùnú jìnnà sí mi, kò sí ẹni tí ó lè dá mi lọ́kàn le. Àwọn ọmọ mi ti di aláìní, nítorí pé àwọn ọ̀tá ti borí wa. “Sioni na ọwọ́ rẹ̀ fún ìrànwọ́, Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó ràn án lọ́wọ́, OLUWA ti pàṣẹ pé, kí àwọn aládùúgbò Jakọbu di ọ̀tá rẹ̀; Jerusalẹmu sì ti di eléèérí láàrin wọn. “Ohun tí ó tọ́ ni OLUWA ṣe, nítorí mo ti ṣe àìgbọràn sí ọ̀rọ̀ rẹ̀; ṣugbọn, ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan, ẹ kíyèsí ìjìyà mi; wọ́n ti kó àwọn ọdọmọbinrin ati ọdọmọkunrin mi lọ sí ìgbèkùn. “Mo ké pe àwọn alajọṣepọ mi, ṣugbọn títàn ni wọ́n tàn mí; àwọn alufaa ati àwọn àgbààgbà mi ṣègbé láàrin ìlú, níbi tí wọn ti ń wá oúnjẹ kiri, tí wọn óo jẹ, kí wọn lè lágbára “Bojúwò mí, OLUWA, nítorí mo wà ninu ìpọ́njú, ọkàn mi ti dàrú, inú mi bàjẹ́, nítorí pé mo ti hùwà ọ̀tẹ̀ lọpọlọpọ. Níta gbangba, ogun ń pa mí lọ́mọ; bákan náà ni ikú ń bẹ ninu ilé. “Gbọ́ bí mo ti ń kérora, kò sí ẹnìkan tí yóo tù mí ninu. Gbogbo àwọn ọ̀tá mi ti gbọ́ nípa ìyọnu mi; inú wọn sì dùn, pé ìwọ ni o kó ìyọnu bá mi. Jẹ́ kí ọjọ́ tí o dá tètè pé, kí àwọn náà lè dàbí mo ti dà. “Ranti gbogbo ìwà ibi wọn, kí o sì jẹ wọ́n níyà; bí o ti jẹ mí níyà, nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi. Ìrora mi pọ̀ ọkàn mi sì rẹ̀wẹ̀sì.” Ẹ wò bí OLUWA ti fi ibinu fi ìkùukùu bo Sioni mọ́lẹ̀. Ó ti wọ́ ògo Israẹli lu láti òkè ọ̀run sórí ilẹ̀ ayé; kò tilẹ̀ ranti àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ ibinu rẹ̀. OLUWA ti pa gbogbo ibùgbé Jakọbu run láìsí àánú. Ó ti fi ibinu wó ibi ààbò Juda lulẹ̀. Ó ti rẹ ìjọba ati àwọn aláṣẹ rẹ̀ sílẹ̀, ó fi àbùkù kàn wọ́n. Ó ti fi ibinu gbígbóná rẹ̀, pa àwọn alágbára Israẹli; ó kọ̀, kò ràn wọ́n lọ́wọ́, nígbà tí àwọn ọ̀tá dojú kọ wọ́n. Ó jó àwọn ọmọ Jakọbu bí iná, ó sì pa gbogbo ohun tí wọn ní run. Ó kẹ́ ọfà rẹ̀ bí ọ̀tá, ó múra bí aninilára. Gbogbo ògo wa ló parun lójú wa, ó sì tú ibinu rẹ̀ jáde bí iná, ninu àgọ́ Sioni. OLUWA ṣe bí ọ̀tá, ó ti pa Israẹli run. Ó ti pa gbogbo ààfin rẹ̀ run, ó sọ àwọn ibi ààbò rẹ̀ di àlàpà ó sì sọ ọ̀fọ̀ ati ẹkún Juda di pupọ. Ó wó àgọ́ rẹ̀ lulẹ̀, bí ìgbà tí eniyan wó ahéré oko. Ó pa gbogbo ibi tí wọ́n ti ń ṣe àwọn àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀ run. OLUWA ti fi òpin sí àwọn àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀, ati ọjọ́ ìsinmi ní Sioni. Ó sì ti fi ibinu gbígbóná rẹ̀, kọ ọba ati alufaa sílẹ̀. OLUWA kò bìkítà fún pẹpẹ rẹ̀ mọ́, ó sì ti kọ ibi mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀. Ó ti fi odi ààfin rẹ̀ lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́; wọ́n pariwo ńlá ninu ilé OLUWA gẹ́gẹ́ bíi ti ọjọ́ àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀. OLUWA ti pinnu láti wó odi Sioni lulẹ̀. Ó fi okùn ìwọ̀n wọ̀n ọ́n, kò sì rowọ́ láti parun. Ó jẹ́ kí ilé ìṣọ́ ati odi ìlú wó lulẹ̀ pẹlu ìbànújẹ́, wọ́n sì di àlàpà papọ̀. Àwọn ẹnubodè rẹ̀ ti rì, wọ́n ti wọlẹ̀; ó ti ṣẹ́ àwọn ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn bodè; ọba rẹ̀ ati àwọn olórí rẹ̀ wà láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn; òfin kò sí mọ́, àwọn wolii rẹ̀ kò sì ríran láti ọ̀dọ̀ OLUWA mọ́. Àwọn àgbààgbà Sioni jókòó lórí ilẹ̀, wọ́n dákẹ́ rọ́rọ́, wọ́n ku eruku sórí, wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀. Àwọn ọmọbinrin Jerusalẹmu doríkodò. Ẹkún sísun ti sọ ojú mi di bàìbàì, ìdààmú bá ọkàn mi; ìbànújẹ́ sì mú kí ó rẹ̀wẹ̀sì nítorí ìparun àwọn eniyan mi, nítorí pé àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ ati àwọn ọmọ ọwọ́ ń dákú lójú pópó láàrin ìlú. Bí wọ́n ti ń dákú láàrin ìlú, bí ẹni tí a ṣá lọ́gbẹ́, tí wọ́n sì ń kú lọ lẹ́yìn ìyá wọn, wọ́n ń sọkún sí àwọn ìyá wọn pé: “Ebi ń pa wá, òùngbẹ sì ń gbẹ wá.” Kí ni mo lè sọ nípa rẹ, kí sì ni ǹ bá fi ọ́ wé, Jerusalẹmu? Kí ni mo lè fi wé ọ, kí n lè tù ọ́ ninu, ìwọ Sioni? Nítorí bí omi òkun ni ìparun rẹ gbòòrò; ta ló lè mú ọ pada bọ̀ sípò? Ìran èké ati ti ẹ̀tàn ni àwọn wolii rẹ ń rí sí ọ; wọn kò fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ hàn ọ́, kí wọ́n lè dá ire rẹ pada, ṣugbọn wọ́n ń ríran èké ati ìran ẹ̀tàn sí ọ. Gbogbo àwọn tí ń rékọjá lọ ń pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí, wọ́n ń pòṣé, wọ́n sì ń mi orí wọn sí ọ, Jerusalẹmu. Wọ́n ń sọ pé: “Ṣé ìlú yìí ni à ń pè ní ìlú tí ó lẹ́wà jùlọ, tí ó jẹ́ ayọ̀ gbogbo ayé?” Gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ ń fi ọ́ ṣẹ̀sín, wọ́n ń pòṣé, wọ́n ń fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà. Wọ́n ń wí pé: “A ti pa á run! Ọjọ́ tí a tí ń retí nìyí; ọwọ́ wa ti tẹ Jerusalẹmu wàyí! A ti rí ohun tí à ń wá!” OLUWA ti ṣe bí ó ti pinnu, ó ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, bí ó ti sọ ní ìgbà àtijọ́. Ó ti wó ọ lulẹ̀ láìṣàánú rẹ; ó ti jẹ́ kí ọ̀tá yọ̀ ọ́, ó ti fún àwọn ọ̀tá rẹ ni agbára kún agbára. Ẹ kígbe sí OLUWA, ẹ̀yin ará Sioni! Ẹ jẹ́ kí omi máa dà lójú yín pòròpòrò tọ̀sán-tòru; ẹ má sinmi, ẹ má sì jẹ́ kí oorun kùn yín. Ẹ dìde, ẹ kígbe lálẹ́, ní àkókò tí àwọn aṣọ́de ń bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́! Ẹ tú ẹ̀dùn ọkàn yín jáde bí omi níwájú OLUWA! Ẹ gbé ọwọ́ ẹ̀bẹ̀ sókè sí i, nítorí ẹ̀mí àwọn ọmọ yín tí ebi ń pa kú lọ ní gbogbo ìkóríta. Wò ó! OLUWA, ṣe akiyesi ohun tí ń ṣẹlẹ̀! Wo àwọn tí ò ń ṣe irú èyí sí! Ṣé ó yẹ kí àwọn obinrin máa jẹ ọmọ wọn? Ọmọ ọwọ́ tí wọn ń tọ́jú! Ṣé ó yẹ kí á pa alufaa ati wolii, ní ibi mímọ́ OLUWA? Àtàwọn ọ̀dọ́, àtàwọn arúgbó wọ́n kú kalẹ̀ lọ lójú pópó, àtàwọn ọdọmọbinrin, àtàwọn ọdọmọkunrin mi, gbogbo wọn ni idà ti pa. Ní ọjọ́ ibinu rẹ ni o pa wọ́n, o pa wọ́n ní ìpakúpa láìṣàánú wọn. O pe àwọn ọ̀tá mi jọ sí mi bí ẹni peniyan síbi àjọ̀dún; kò sì sí ẹni tí ó yè ní ọjọ́ ibinu rẹ, OLUWA. Ọ̀tá mi pa àwọn ọmọ mi run, àwọn tí mo tọ́, tí mo sì fẹ́ràn. Èmi ni mo mọ bí eniyan tií rí ìpọ́njú, tí mo mọ bí Ọlọrun tií fi ibinu na eniyan ní pàṣán. Ó lé mi wọ inú òkùnkùn biribiri. Dájúdájú, ó ti dojú kọ mí, ó sì bá mi jà léraléra tọ̀sán-tòru. Ó ti jẹ́ kí n rù kan egungun, ó sì ti fọ́ egungun mi. Ó dótì mí, ó fi ìbànújẹ́ ati ìṣẹ́ yí mi káàkiri. Ó fi mí sinu òkùnkùn bí òkú tí ó ti kú láti ọjọ́ pípẹ́. Ó mọ odi yí mi ká, ó sì fi ẹ̀wọ̀n wúwo dè mí, kí n má baà lè sálọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ké pè é fún ìrànlọ́wọ́, sibẹsibẹ kò gbọ́ adura mi. Ó to òkúta gbígbẹ́ dí ọ̀nà mi, ó mú kí ọ̀nà mí wọ́. Ó ba dè mí bí ẹranko ìjàkùmọ̀, ó lúgọ bíi kinniun, Ó wọ́ mi kúrò lójú ọ̀nà mi, ó fà mí ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, ó sì ti sọ mí di alailẹnikan. Ó kẹ́ ọfà, ó fa ọrun rẹ̀, ó sì fi mí ṣe ohun ìtafàsí. Ó mú gbogbo ọfà tí ó wà ninu apó rẹ̀ ó ta wọ́n mọ́ mi lọ́kàn. Mo wá di ẹni yẹ̀yẹ́ lọ́dọ̀ gbogbo eniyan, ẹni tí wọ́n fi ń kọrin tọ̀sán-tòru. Ó mú kí ọkàn mi kún fún ìbànújẹ́, ó fún mi ní iwọ mu ní àmuyó. Ó fẹnu mi gbolẹ̀, títí yangí fi ká mi léyín; ó gún mi mọ́lẹ̀ ninu eruku Ọkàn mi kò ní alaafia, mo ti gbàgbé ohun tí ń jẹ́ ayọ̀. Nítorí náà, mo wí pé, “Ògo mi ti tán, ati gbogbo ohun tí mò ń retí lọ́dọ̀ OLUWA.” Ranti ìyà ati ìbànújẹ́ mi, ati ìrora ọkàn mi! Mò ń ranti nígbà gbogbo, ọkàn mi sì ń rẹ̀wẹ̀sì. Ṣugbọn mo tún ń ranti nǹkankan, mo sì ní ìrètí. Nítorí pé Ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀ kò nípẹ̀kun, àánú rẹ̀ kò sì lópin; ọ̀tun ni wọ́n láràárọ̀, òtítọ́ rẹ̀ pọ̀. Ọkàn mi wí pé, “OLUWA ni ìpín mi, nítorí náà lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí mi wà.” OLUWA a máa ṣe oore fún àwọn tí wọn dúró dè é, tí wọn sì ń wá ojurere rẹ̀. Ó dára kí eniyan dúró jẹ́ẹ́, de ìgbàlà OLUWA. Ó dára kí eniyan foríti àjàgà ìtọ́sọ́nà ní ìgbà èwe. Kí ó fi ọwọ́ lẹ́rán, kí ó dákẹ́, kí ó sì máa wòye, nítorí Ọlọrun ni ó gbé àjàgà náà kọ́ ọ lọ́rùn. Kí ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, bóyá ìrètí lè tún wà fún un. Kí ó kọ etí rẹ̀ sí ẹni tí ó fẹ́ gbá a létí, kí wọ́n sì fi àbùkù kàn án. Nítorí OLUWA kò ní ta wá nù títí lae. Bí ó tilẹ̀ mú kí ìbànújẹ́ dé bá wa, yóo ṣàánú wa, yóo tù wá ninu, gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀. Nítorí pé kì í kàn déédé ni eniyan lára tabi kí ó mú ìbànújẹ́ dé bá eniyan láìní ìdí. OLUWA kò faramọ́ pé kí á máa ni àwọn ẹlẹ́wọ̀n lára lórí ilẹ̀ ayé, kí á máa já ẹ̀tọ́ olódodo gbà lọ́wọ́ rẹ̀ níwájú Ọ̀gá Ògo, tabi kí á du eniyan ní ìdájọ́ òdodo. Ta ló pàṣẹ nǹkankan rí tí ó sì rí bẹ́ẹ̀, láìjẹ́ pé OLUWA ló fi ọwọ́ sí i? Àbí kì í ṣe láti ẹnu Ọ̀gá Ògo ni rere ati burúkú ti ń jáde? Kí ló dé tí ẹ̀dá alààyè kan yóo fi máa ráhùn nígbà tí ó bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀? Ẹ jẹ́ kí á yẹ ara wa wò, kí á tún ọ̀nà wa ṣe, kí á sì yipada sí ọ̀dọ̀ OLUWA. Ẹ jẹ́ kí á gbé ojú wa sókè, kí á ra ọwọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọrun ọ̀run: “A ti ṣẹ̀, a sì ti ṣoríkunkun, ìwọ OLUWA kò sì tíì dáríjì wá. “O gbé ibinu wọ̀ bí ẹ̀wù, ò ń lépa wa, o sì ń pa wá láì ṣàánú wa. O ti fi ìkùukùu bo ara rẹ, tóbẹ́ẹ̀ tí adura kankan kò lè kọjá sọ́dọ̀ rẹ. O ti sọ wá di ààtàn ati ohun ẹ̀gbin láàrin àwọn eniyan. “Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ń wẹnu sí wa lára. Ẹ̀rù ati ìṣubú, ìsọdahoro ati ìparun ti dé bá wa. Omijé ń dà pòròpòrò lójú mi, nítorí ìparun àwọn eniyan mi. “Omijé yóo máa dà pòròpòrò lójú mi láì dáwọ́ dúró, ati láìsinmi. Títí OLUWA yóo fi bojú wo ilẹ̀ láti ọ̀run wá, tí yóo sì rí wa. Ìbànújẹ́ bá mi, nígbà tí mo rí ibi tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọbinrin ìlú mi. “Àwọn tí ń bá mi ṣọ̀tá láìnídìí ń dọdẹ mi bí ìgbà tí eniyan ń dọdẹ ẹyẹ. Wọ́n jù mí sinu ihò láàyè, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ òkúta lù mí mọ́lẹ̀. Omi bò mí mọ́lẹ̀, mo ní, ‘Mo ti gbé.’ “Mo ké pe orúkọ rẹ, OLUWA, láti inú kòtò jíjìn. O gbọ́ ẹ̀bẹ̀ tí mò ń bẹ̀ pé, ‘Má ṣe di etí rẹ sí igbe tí mò ń ké fún ìrànlọ́wọ́.’ O súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi nígbà tí mo pè ọ́, o dá mi lóhùn pé, ‘Má bẹ̀rù.’ “OLUWA, o ti gba ìjà mi jà, o ti ra ẹ̀mí mi pada. O ti rí nǹkan burúkú tí wọ́n ṣe sí mi, OLUWA, dá mi láre. O ti rí gbogbo ìgbẹ̀san wọn, ati gbogbo ète wọn lórí mi. “O ti gbọ́ bí wọn tí ń pẹ̀gàn mi, OLUWA, ati gbogbo ète wọn lórí mi. Gbogbo ọ̀rọ̀ ati èrò àwọn ọ̀tá mi sí mi: ibi ni lojoojumọ. Kíyèsí i, wọn ìbáà jókòó, wọn ìbáà dìde dúró, èmi ni wọ́n máa fi ń kọrin. “O óo san ẹ̀san fún wọn, OLUWA, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Jẹ́ kí ojú inú wọn fọ́, kí ègún rẹ sì wà lórí wọn. Fi ibinu lépa wọn, OLUWA, sì pa wọ́n run láyé yìí.” Wo bí wúrà ti dọ̀tí, tí ojúlówó wúrà sì yipada; tí àwọn òkúta Tẹmpili mímọ́ sì fọ́nká ní gbogbo ìkóríta. Ẹ wo àwọn ọdọmọkunrin Sioni, àwọn ọmọ tí wọn níye lórí bí ojúlówó wúrà, tí a wá ń ṣe bí ìkòkò amọ̀; àní, bí ìkòkò amọ̀ lásánlàsàn. Àwọn ajáko a máa fún àwọn ọmọ wọn lọ́mú. Ṣugbọn àwọn eniyan mi ti di ìkà, bí ògòǹgò inú aṣálẹ̀. Ahọ́n ọmọ ọmú lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu rẹ̀ nítorí òùngbẹ. Àwọn ọmọde ń tọrọ oúnjẹ, ṣugbọn kò sí ẹni tí ó fún wọn. Àwọn tí wọn tí ń jẹ oúnjẹ àdídùn di ẹni tí ń ṣa ilẹ̀ jẹ kiri ní ìgboro. Àwọn tí wọn tí ń fi aṣọ àlàárì bora di ẹni tí ń sùn lórí òkítì eérú. Ìjìyà àwọn eniyan mi pọ̀ ju ti àwọn ará Sodomu lọ, Sodomu tí ó parun lójijì, láìjẹ́ pé eniyan fi ọwọ́ kàn án. Àwọn olórí wọn kò ní àléébù kankan, Ọwọ́ wọn mọ́, inú wọn funfun nini, wọ́n dára ju egbin lọ, ẹwà wọn sì dàbí ẹwà iyùn. Ṣugbọn nisinsinyii, ojú wọn dúdú ju èédú lọ, kò sí ẹni tí ó dá wọn mọ̀ láàrin ìgboro, awọ ara wọn ti hunjọ lórí egungun wọn, wọ́n wá gbẹ bí igi. Ti àwọn tí wọ́n kú ikú ogun sàn ju àwọn tí wọ́n kú ikú ebi lọ, àwọn tí ebi pa joró dójú ikú, nítorí àìsí oúnjẹ ninu oko. Àwọn obinrin tí wọn ní ojú àánú ti fi ọwọ́ ara wọn se ọmọ wọn jẹ, wọ́n fi ọmọ wọn ṣe oúnjẹ jẹ, nígbà tí ìparun dé bá àwọn eniyan mi. OLUWA bínú gidigidi, ó tú ibinu gbígbóná rẹ̀ jáde. OLUWA dá iná kan ní Sioni tí ó jó ìpìlẹ̀ rẹ̀ run. Àwọn ọba ayé kò gbàgbọ́, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo aráyé kò gbà pé ó lè ṣẹlẹ̀, pé ọ̀tá lè wọ ẹnubodè Jerusalẹmu. Ẹ̀ṣẹ̀ àwọn wolii rẹ̀ ló fa èyí, ati àìdára àwọn alufaa rẹ̀, tí wọ́n pa olódodo láàrin ìlú. Wọ́n ń káàkiri bí afọ́jú láàrin ìgboro, ẹ̀jẹ̀ àwọn tí wọ́n pa sọ wọ́n di aláìmọ́ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè fọwọ́ kan aṣọ wọn. Àwọn eniyan ń kígbe lé wọn lórí pé; “Ẹ máa lọ! Ẹ̀yin aláìmọ́! Ẹ máa kóra yín lọ! Ẹ má fi ọwọ́ kan nǹkankan!” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe di ìsáǹsá ati alárìnkiri, nítorí àwọn eniyan ń wí láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè pé, “Àwọn wọnyi kò gbọdọ̀ bá wa gbé pọ̀ mọ́.” OLUWA fúnrarẹ̀ ti tú wọn ká, kò sì ní náání wọn mọ́. Kò ní bọlá fún àwọn alufaa wọn, kò sì ní fi ojurere wo àwọn àgbààgbà. A wọ̀nà títí ojú wa di bàìbàì, asán ni ìrànlọ́wọ́ tí à ń retí jásí. A wọ̀nà títí fún ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ orílẹ̀-èdè tí kò lè gbani là. Àwọn eniyan ń ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ wa, tóbẹ́ẹ̀ tí a kò lè rìn gaara ní ìgboro. Ìparun wa súnmọ́lé, ọjọ́ ayé wa ti níye, nítorí ìparun wa ti dé. Àwọn tí wọn ń lépa wa yára ju idì tí ń fò lójú ọ̀run lọ. Wọ́n ń lé wa lórí òkè, wọ́n sì ba dè wá ninu aṣálẹ̀. Ẹ̀mí àwa ẹni àmì òróró OLUWA bọ́ sinu kòtò wọn, OLUWA tí à ń sọ nípa rẹ̀ pé, lábẹ́ òjìji rẹ̀ ni a óo máa gbé láàrin àwọn orílẹ̀-èdè. Ẹ máa yọ̀, kí inú yín sì máa dùn, ẹ̀yin ará Edomu, tí ń gbé ilẹ̀ Usi. Ṣugbọn ife náà yóo kọjá lọ́dọ̀ yín, ẹ óo mu ún ní àmuyó, ẹ óo sì tú ara yín síhòòhò. Ẹ ti jìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín ní àjẹpé, ẹ̀yin ará Sioni, OLUWA kò ní fi yín sílẹ̀ ní ìgbèkùn mọ́. Ṣugbọn yóo jẹ ẹ̀yin ará Edomu níyà fún ẹ̀ṣẹ̀ yín, yóo tú àṣírí ẹ̀ṣẹ̀ yín. OLUWA, ranti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa, Ṣe akiyesi ẹ̀sín wa. Àwọn ilẹ̀ àjogúnbá ẹni ẹlẹ́ni, ilé wa sì ti di ti àwọn àjèjì. A ti di aláìníbaba, ọmọ òrukàn àwọn ìyá wa kò yàtọ̀ sí opó. Owó ni a fi ń ra omi tí à ń mu, rírà ni a sì ń ra igi tí a fi ń dáná. Àwọn tí wọn ń lépa wa ti bá wa, ó ti rẹ̀ wá, a kò sì ní ìsinmi. A ti fa ara wa kalẹ̀ fún àwọn ará Ijipti ati àwọn ará Asiria nítorí oúnjẹ tí a óo jẹ. Àwọn baba wa ni wọ́n dẹ́ṣẹ̀, àwọn sì ti kú, ṣugbọn àwa ni à ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Àwọn ẹrú ní ń jọba lé wa lórí, kò sì sí ẹni tí yóo gbà wá lọ́wọ́ wọn. Ẹ̀mí wa ni à ń fi wéwu, kí á tó rí oúnjẹ, nítorí ogun tí ó wà ninu aṣálẹ̀. Awọ ara wa gbóná bí iná ààrò, nítorí ìyàn tí ó mú lọpọlọpọ. Tipátipá ni wọ́n fi ń bá àwọn obinrin lòpọ̀ ní Sioni, ati àwọn ọmọbinrin tí wọn kò tíì mọ ọkunrin ní Juda. Wọ́n fi okùn so ọwọ́ àwọn olórí rọ̀, wọn kò sì bọ̀wọ̀ fún àwọn àgbààgbà. Wọ́n fi ipá mú àwọn ọdọmọkunrin pé kí wọn máa lọ ọlọ, àwọn ọmọde ru igi títí àárẹ̀ mú wọn! Àwọn àgbààgbà ti sá kúrò ní ẹnubodè; àwọn ọdọmọkunrin sì ti dákẹ́ orin kíkọ. Inú wa kò dùn mọ́; ijó wa ti yipada, ó ti di ọ̀fọ̀. Adé ti ṣíbọ́ lórí wa! A gbé! Nítorí pé a ti dẹ́ṣẹ̀, nítorí náà, ọkàn wa ti rẹ̀wẹ̀sì; ojú wa sì ti di bàìbàì. Nítorí òkè Sioni tí ó di ahoro; tí àwọn ọ̀fàfà sì ń ké lórí rẹ̀. Ṣugbọn ìwọ OLUWA ni ó jọba títí ayé, ìtẹ́ rẹ sì wà láti ìrandíran. Kí ló dé tí o fi gbàgbé wa patapata? Tí o sì kọ̀ wá sílẹ̀ fún ìgbà pípẹ́? Mú wa pada sọ́dọ̀ ara rẹ, OLUWA, kí á lè pada sí ipò wa. Mú àwọn ọjọ́ àtijọ́ wa pada. Ṣé o ti kọ̀ wá sílẹ̀ patapata ni? Àbí o sì tún ń bínú sí wa, inú rẹ kò tíì rọ̀? Ní ọjọ́ karun-un oṣù kẹrin, ní ọgbọ̀n ọdún, èmi, Isikiẹli, ọmọ Busi, wà láàrin àwọn tí wọ́n kó ní ìgbèkùn lọ sí ilẹ̀ Babiloni. A wà lẹ́bàá odò Kebari, mo bá rí i tí ojú ọ̀run ṣí sílẹ̀; mo sì rí ìran Ọlọrun. Lọ́jọ́ karun-un oṣù náà, tíí ṣe ọdún karun-un tí wọ́n ti mú ọba Jehoiakini lọ sí ìgbèkùn, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀ ní ilẹ̀ àwọn ará Kalidea lẹ́bàá odò Kebari; agbára OLUWA sì sọ̀kalẹ̀ sí mi lára. Ninu ìran náà, mo rí i tí ìjì kan ń jà bọ̀ láti ìhà àríwá, pẹlu ìkùukùu ńlá tí ìmọ́lẹ̀ ńlá ati iná tí ń kọ mànàmànà yí ìjì náà ká, ààrin iná náà sì dàbí idẹ dídán tí ń kọ mànà. Láàrin iná yìí, mo rí àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin kan, wọ́n dàbí eniyan. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu wọn ní ojú mẹrin mẹrin ati ìyẹ́ mẹrin mẹrin. Ẹsẹ̀ wọn tọ́, àtẹ́lẹsẹ̀ wọn sì dàbí pátákò mààlúù, ó ń kọ mànà bíi idẹ. Wọ́n ní ọwọ́ eniyan lábẹ́ ìyẹ́ wọn mẹrẹẹrin, wọ́n ní ojú mẹ́rin ati ìyẹ́ mẹ́rin. Báyìí ni ojú àwọn mẹrẹẹrin ati ìyẹ́ wọn rí: Ìyẹ́ wọn ń kan ara wọn; bí wọ́n bá ń rìn, olukuluku wọn á máa lọ siwaju tààrà, láìyà sí ibikíbi, bí wọn tí ń lọ. Báyìí ni ojú wọn rí: olukuluku wọn ní ojú eniyan níwájú, àwọn mẹrẹẹrin ní ojú kinniun lápá ọ̀tún, wọ́n ní ojú akọ mààlúù lápá òsì, wọ́n sì ní ojú ẹyẹ idì lẹ́yìn. Wọ́n na ìyẹ́ wọn sókè, ọ̀kọ̀ọ̀kan na ìyẹ́ meji meji kan ìyẹ́ ẹni tí ó kángun sí i, wọ́n sì fi ìyẹ́ meji meji bora. Olukuluku kọjú sí ìhà mẹrin, ó sì lè lọ tààrà sí ìhà ibi tí ẹ̀mí rẹ̀ bá darí sí láì ṣẹ̀ṣẹ̀ yí ojú pada kí ó tó máa lọ. Nǹkankan wà láàrin àwọn ẹ̀dá alààyè náà tí ó dàbí ẹ̀yinná tí ń jó. Ó ń lọ sókè sódò láàrin wọn bí ahọ́n iná. Iná náà mọ́lẹ̀, ó sì ń kọ mànàmànà. Àwọn ẹ̀dá alààyè náà ń já lọ sókè sódò bí ìgbà tí manamana bá ń kọ. Bí mo ti ń wo àwọn ẹ̀dá alààyè náà, mo rí àgbá kẹ̀kẹ́ mẹrin lórí ilẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, àgbá kọ̀ọ̀kan fún ọ̀kọ̀ọ̀kan. Ìrísí àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà ati bí a ti ṣe wọ́n nìyí: wọ́n ń dán yànrànyànràn bí òkúta kirisolite. Bákan náà ni àwọn mẹrẹẹrin rí. A ṣe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn bí ìgbà tí àgbá meji bá wọ inú ara wọn. Bí wọ́n ti ń lọ, ìhà ibi tí wọn bá fẹ́ ninu ìhà mẹrẹẹrin ni wọ́n lè máa lọ láì ṣẹ̀ṣẹ̀ yíjú pada, kí wọ́n tó máa lọ. (Àgbá mẹrẹẹrin ní irin tẹẹrẹtẹẹrẹ tí ó so ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn pọ̀). Wọ́n ga, wọ́n ba eniyan lẹ́rù. Àwọn àgbá mẹrẹẹrin ní ojú yíká wọn. Bí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá ti ń lọ ni àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà a máa yí tẹ̀lé wọn, bí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá gbéra nílẹ̀ àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà a sì gbéra nílẹ̀ pẹlu. Ibikíbi tí ẹ̀mí bá fẹ́ lọ ni àwọn ẹ̀dá náà máa ń lọ, àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà a sì máa yí lọ pẹlu wọn, nítorí pé ninu àwọn àgbá náà ni ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè náà wà. Bí wọn bá ń lọ àwọn àgbá náà a máa yí lọ pẹlu wọn. Bí wọ́n bá dúró àwọn àgbá náà a dúró. Bí wọn bá gbéra nílẹ̀, àwọn àgbá náà a gbéra nílẹ̀, nítorí pé ninu àwọn àgbá wọnyi ni ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè náà wà. Kinní kan bí awọsanma tí ó ń dán bíi Kristali wà lórí àwọn ẹ̀dá alààyè náà, ó tàn bo gbogbo orí wọn. Lábẹ́ kinní bí awọsanma yìí ni àwọn ìyẹ́ wọn ti nà jáde, wọ́n kan ara wọn, àwọn ẹ̀dá alààyè náà ní ìyẹ́ meji meji tí wọ́n fi bora. Bí wọ́n ti ń lọ, mo gbọ́ ariwo ìyẹ́ wọn, ó dàbí ariwo odò ńlá, bí ààrá Olodumare, bí ariwo ìdágìrì ọpọlọpọ àwọn ọmọ ogun. Bí wọ́n bá dúró, wọn a ká ìyẹ́ wọn wálẹ̀, nǹkankan a sì máa dún lókè awọsanma tí ó wà lórí wọn. Bí wọn bá ti dúró, wọn a ká ìyẹ́ wọn wálẹ̀. Mo rí kinní kan lókè awọsanma tí ó wà lórí wọn, ó dàbí ìtẹ́ tí a fi òkúta safire ṣe; mo sì rí kinní kan tí ó dàbí eniyan, ó jókòó lórí nǹkankan bí ìtẹ́ náà. Mo wò ó láti ibi tí ó dàbí ìbàdí rẹ̀ lọ sókè, ó rí bíi bàbà dídán, ó dàbí iná yíká. Mo wò ó láti ibi ìbàdí lọ sí ìsàlẹ̀, ó dàbí iná. Ìmọ́lẹ̀ sì wà ní gbogbo àyíká rẹ̀. Ìmọ́lẹ̀ tí ó yí i ká dàbí òṣùmàrè tí ó yọ ninu ìkùukùu lákòókò òjò. Bẹ́ẹ̀ ni àfiwé ìfarahàn ògo OLUWA rí. Nígbà tí mo rí i, mo dojúbolẹ̀, mo bá gbọ́ ohùn ẹnìkan tí ń sọ̀rọ̀. Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ eniyan, dìde dúró, mo fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀.” Bí ó ti ń bá mi sọ̀rọ̀, ẹ̀mí OLUWA wọ inú mi, ó gbé mi nàró, mo sì gbọ́ bí ó ti ń bá mi sọ̀rọ̀. Ó ní, “Ọmọ eniyan, mo rán ọ sí àwọn ọmọ Israẹli, orílẹ̀-èdè àwọn ọlọ̀tẹ̀, àwọn tí wọ́n ń ṣọ̀tẹ̀ sí mi. Àwọn ati àwọn baba ńlá wọn ṣì tún ń bá mi ṣọ̀tẹ̀ títí di òní olónìí. Aláfojúdi ati olóríkunkun ẹ̀dá ni wọ́n. Mò ń rán ọ sí wọn kí o lè sọ ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun wí fún wọn. Bí wọn bá fẹ́ kí wọn gbọ́, bí wọn sì fẹ́, kí wọn má gbọ́. (Nítorí pé ọlọ̀tẹ̀ kúkú ni wọ́n), ṣugbọn wọn yóo mọ̀ pé Wolii kan ti wà láàrin wọn. “Ṣugbọn ìwọ ọmọ eniyan, má jẹ́ kí ẹ̀rù wọn bà ọ́, má sì bẹ̀rù ọ̀rọ̀ tí wọn ń sọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀gún ọ̀gàn ati ẹ̀wọ̀n agogo yí ọ ká, tí o sì jókòó láàrin àwọn àkeekèé, má ṣe bẹ̀rù ohunkohun tí wọn bá wí. Má jẹ́ kí ojú wọn dẹ́rù bà ọ́, nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n. O óo sọ ohun tí mo bá wí fún wọn, wọn ìbáà gbọ́, wọn ìbáà má gbọ́; nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ kúkú ni wọ́n. “Ṣugbọn ìwọ, ọmọ eniyan, fetí sí ohun tí mò ń sọ fún ọ. Má dìtẹ̀ bí àwọn ọmọ ìdílé ọlọ̀tẹ̀ wọnyi. La ẹnu rẹ kí o sì jẹ ohun tí n óo fún ọ.” Nígbà tí mo wò, mo rí ọwọ́ tí ẹnìkan nà sí mi, ìwé kan tí a ká sì wà ninu rẹ̀. Ó tẹ́ ìwé náà siwaju mi; mo sì rí i pé wọ́n kọ nǹkan sí i ní àtojú àtẹ̀yìn. Ọ̀rọ̀ ẹkún, ati ọ̀rọ̀ ọ̀fọ̀, ati ègún ni wọ́n kọ sinu rẹ̀. Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ Eniyan, jẹ ohun tí a fún ọ; jẹ ìwé tí a ká yìí, kí o sì lọ bá ilé Israẹli sọ̀rọ̀.” Mo bá la ẹnu, ó sì fún mi ní ìwé náà jẹ. Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ eniyan, jẹ ìwé tí a ká, tí mo fún ọ yìí, kí o sì yó.” Mo bá jẹ ẹ́, ó sì dùn bí oyin lẹ́nu mi. Ó tún sọ fún mi pé, “Ọmọ eniyan, lọ bá àwọn ọmọ Israẹli kí o sọ ọ̀rọ̀ mi fún wọn. Kì í sá ṣe àwọn tí wọn ń sọ èdè mìíràn tí ó ṣòro gbọ́, ni mo rán ọ sí, àwọn ọmọ ilé Israẹli ni. N kò rán ọ sí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ń sọ èdè mìíràn tí yóo ṣòro fún ọ láti gbọ́. Dájúdájú, bí ó bá jẹ́ irú wọn ni mo rán ọ sí, wọn ìbá gbọ́ tìrẹ. Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli kò ní gbọ́ tìrẹ, nítorí pé wọn kò fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Olóríkunkun ati ọlọ́kàn líle ni gbogbo wọn. Mo ti mú kí ojú rẹ le sí tiwọn. Bí òkúta adamanti ṣe le ju òkúta akọ lọ ni mo ṣe mú kí orí rẹ le ju orí wọn lọ. Má bẹ̀rù, má sì ṣe jẹ́ kí ojú wọn já ọ láyà, nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.” Ó tún sọ fún mi, pé, “Ọmọ eniyan, fi etí sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí n óo bá ọ sọ, kí o sì fi wọ́n sọ́kàn. Lọ bá àwọn eniyan rẹ tí wọ́n wà ní ìgbèkùn, kí o sọ ohun tí OLUWA Ọlọrun sọ fún wọn; wọn ìbáà gbọ́, wọn ìbáà má sì gbọ́.” Nígbà náà ni ẹ̀mí gbé mi dìde, mo sì gbọ́ ìró kan lẹ́yìn mi tí ó dàbí ariwo ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá, ó ní, “Ẹ fi ìyìn fún ìfarahàn ògo OLUWA ní ibùgbé rẹ̀.” Ìró ìyẹ́ àwọn ẹ̀dá alààyè náà ni mò ń gbọ́ tí wọn ń kan ara wọn, ati ìró àgbá wọn; ó dàbí ìró ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá. Nígbà náà ni ẹ̀mí gbé mi dìde, ó sì gbé mi lọ. Tìbínú-tìbínú ni mo sì fi ń lọ. Ẹ̀mí OLUWA ni ó gbé mi lọ pẹlu agbára. Mo bá dé Teli Abibu lọ́dọ̀ àwọn ìgbèkùn tí wọn ń gbé ẹ̀bá odò Kebari. Ọjọ́ meje ni mo fi wà pẹlu wọn, tí mo jókòó tì wọ́n, tí mò ń wò wọ́n tìyanu-tìyanu. Lẹ́yìn ọjọ́ keje, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Ọmọ eniyan, mo ti fi ọ́ ṣe olùṣọ́ fún ilé Israẹli. Nígbàkúùgbà tí o bá gbọ́ ohunkohun lẹ́nu mi, o gbọdọ̀ kìlọ̀ fún wọn. Bí mo bá sọ fún eniyan burúkú pé dájúdájú yóo kú, ṣugbọn tí o kò kìlọ̀ fún un pé kí ó yipada kúrò ní ọ̀nà ibi tí ó ń rìn kí ó lè yè, eniyan burúkú náà yóo kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; ṣugbọn lọ́wọ́ rẹ ni n óo ti bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Ṣugbọn bí o bá kìlọ̀ fún eniyan burúkú, tí kò bá yipada kúrò ninu iṣẹ́ burúkú tí ó ń ṣe, tabi ọ̀nà ibi tí ó ń tọ̀; yóo kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn ìwọ óo gba ara rẹ là. “Bẹ́ẹ̀ náà sì ni bí olódodo bá yipada kúrò ninu òdodo rẹ̀, tí ó bá dẹ́ṣẹ̀, tí mo sì gbé ohun ìkọsẹ̀ kan siwaju rẹ̀, yóo kú, nítorí pé o kò kìlọ̀ fún un, yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, a kò sì ní ranti iṣẹ́ òdodo rẹ̀ tí ó ti ṣe; ṣugbọn n óo bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ. Ṣugbọn bí o bá kìlọ̀ fún olódodo náà pé kí ó má dẹ́ṣẹ̀, tí kò sì dẹ́ṣẹ̀, dájúdájú yóo yè, nítorí pé ó gbọ́ ìkìlọ̀; ìwọ náà yóo sì gba ẹ̀mí ara rẹ là.” Ẹ̀mí OLUWA sì wà lára mi, ó sọ fún mi pé, “Dìde, lọ sí àfonífojì, níbẹ̀ ni n óo ti bá ọ sọ̀rọ̀.” Mo bá dìde, mo jáde lọ sí àfonífojì. Mo rí ìfarahàn ògo OLUWA níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti rí i lẹ́bàá odò Kebari, mo bá dojúbolẹ̀. Ṣugbọn ẹ̀mí Ọlọrun kó sí mi ninu, ó sì gbé mi nàró; ó bá mi sọ̀rọ̀, ó sọ fún mi pé, “Lọ ti ara rẹ mọ́ ilé rẹ. Ìwọ ọmọ eniyan, wò ó! A óo na okùn lé ọ lórí, a óo sì fi okùn náà dè ọ́, kí o má baà lè jáde sí ààrin àwọn eniyan. N óo mú kí ahọ́n rẹ lẹ̀ mọ́ ọ lẹ́nu kí o sì ya odi, kí o má baà lè kìlọ̀ fún wọn, nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni ìdílé wọn. Ṣugbọn bí mo bá bá ọ sọ̀rọ̀ tán, n óo là ọ́ lóhùn, o óo sì sọ ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun bá sọ fún wọn. Ẹni tí ó bá fẹ́, kí ó gbọ́, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó má gbọ́, nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni ìdílé wọn.” OLUWA ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, mú bulọọku kan kí o gbé e ka iwájú rẹ, kí o sì ya àwòrán ìlú Jerusalẹmu sórí rẹ̀. Kó àwọn nǹkan tí wọ́n fi ń dóti ìlú tì í. Bu yẹ̀ẹ̀pẹ̀ sí i lẹ́gbẹ̀ẹ́ kí ọ̀nà dé ibẹ̀. Fi àgọ́ àwọn jagunjagun sí i, kí o wá gbẹ́ kòtò ńlá yí i ká. Wá irin pẹlẹbẹ kan tí ó fẹ̀, kí o gbé e sí ààrin ìwọ ati ìlú náà, kí ó dàbí ògiri onírin. Dojú kọ ọ́ bí ìlú tí a gbógun tì; kí o ṣebí ẹni pé ò ń gbógun tì í. Èyí yóo jẹ́ àmì fún ilé Israẹli. “Lẹ́yìn náà, fi ẹ̀gbẹ́ rẹ òsì dùbúlẹ̀, kí o sì di ìjìyà àwọn ọmọ ilé Israẹli lé ara rẹ lórí. O óo ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún iye ọjọ́ tí o bá fi dùbúlẹ̀. Mo ti fún ọ ní irinwo ọjọ́ ó dín mẹ́wàá (390) láti fi ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli. Èyí ni iye ọdún tí wọ́n fi dẹ́ṣẹ̀. Nígbà tí o bá parí iye ọjọ́ yìí, o óo fi ẹ̀gbẹ́ rẹ ọ̀tún lélẹ̀, o óo sì fi ogoji ọjọ́ ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ ilé Juda; ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tí o óo fi dùbúlẹ̀ dúró fún ọdún kọ̀ọ̀kan tí wọ́n fi dẹ́ṣẹ̀. “Lẹ́yìn náà, kọjú sí Jerusalẹmu, ìlú tí a gbógun tì, ká aṣọ kúrò ní apá rẹ kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí i. Wò ó! N óo dè ọ́ lókùn mọ́lẹ̀, tí o kò fi ní lè yí ẹ̀gbẹ́ pada títí tí o óo fi parí iye ọjọ́ tí o níláti fi gbé ogun tì í. “Mú alikama ati ọkà baali, ẹ̀wà ati lẹntili, jéró ati ọkà sipẹliti, kí o kó wọn sinu ìkòkò kan, kí o sì fi wọ́n ṣe burẹdi fún ara rẹ. Òun ni o óo máa jẹ fún irinwo ọjọ́ ó dín mẹ́wàá (390), tí o óo fi fi ẹ̀gbẹ́ lélẹ̀. Wíwọ̀n ni o óo máa wọn oúnjẹ tí o óo máa jẹ, ìwọ̀n oúnjẹ òòjọ́ rẹ yóo jẹ́ ogún ṣekeli, ẹ̀ẹ̀kan lojumọ ni o óo sì máa jẹ ẹ́. Wíwọ̀n ni o óo máa wọn omi tí o óo máa mu pẹlu; ìdá mẹfa òṣùnwọ̀n hini ni omi tí o óo máa mu ní ọjọ́ kan, ẹ̀ẹ̀kan lojumọ ni o óo sì máa mu ún. O óo jẹ ẹ́ bí àkàrà ọkà baali dídùn; ìgbẹ́ eniyan ni o óo máa fi dá iná tí o óo máa fi dín in lójú wọn.” OLUWA ní: “Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli yóo ṣe máa jẹ oúnjẹ wọn ní àìmọ́, láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí òun óo lé wọn sí.” Mo bá dáhùn pé, “Háà! OLUWA Ọlọrun, n kò sọ ara mi di aláìmọ́ rí láti ìgbà èwe mi títí di ìsinsìnyìí, n kò jẹ òkú ẹran rí, tabi ẹran tí ẹranko pa, bẹ́ẹ̀ ni ẹran àìmọ́ kankan kò kan ẹnu mi rí.” OLUWA bá wí fún mi pé, “Kò burú, n óo jẹ́ kí o fi ìgbẹ́ mààlúù dáná láti fi dín àkàrà rẹ, dípò ìgbẹ́ eniyan.” Ó tún fi kun fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, n óo mú kí oúnjẹ wọ́n ní Jerusalẹmu tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé ìbẹ̀rù ni wọn óo máa fi wá oúnjẹ tí wọn óo máa jẹ, wíwọ̀n ni wọn óo sì máa wọn omi mu pẹlu ìpayà. N óo ṣe bẹ́ẹ̀ kí wọ́n lè ṣe aláìní oúnjẹ ati omi, kí wọ́n lè máa wo ara wọn pẹlu ìpayà, kí wọ́n sì parun nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” OLUWA ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, mú idà kan tí ó bá mú, lò ó gẹ́gẹ́ bí abẹ ìfárí, kí o fi fá orí ati irùngbọ̀n rẹ. Mú òṣùnwọ̀n tí a fi ń wọn nǹkan kí o fi pín irun tí o bá fá sí ọ̀nà mẹta. Jó ìdámẹ́ta rẹ̀ ninu iná láàrin ìlú, ní ìgbà tí ọjọ́ tí a fi dóti ìlú náà bá parí. Máa fi idà gé ìdámẹ́ta, kí o sì fọ́n ọn káàkiri lẹ́yìn ìlú, fọ́n ìdámẹ́ta yòókù káàkiri sinu afẹ́fẹ́, n óo sì fa idà yọ tẹ̀lé e. Mú díẹ̀ ninu irun náà kí o dì í sí etí ẹ̀wù rẹ. Mú díẹ̀ ninu èyí tí o dì sí etí ẹ̀wù, jù ú sinu iná kí ó jóná; iná yóo sì ti ibẹ̀ ṣẹ́ sí gbogbo ilé Israẹli.” OLUWA Ọlọrun ní: “Jerusalẹmu nìyí. Mo ti fi í sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, mo sì ti fi àwọn agbègbè yí i ká. Ó ti tàpá sí òfin mi ju àwọn orílẹ̀-èdè yòókù lọ, ó sì ti kọ ìlànà mi sílẹ̀ ju àwọn agbègbè tí ó yí i ká lọ. Wọ́n kọ òfin mi sílẹ̀, wọn kò sì tẹ̀lé ìlànà mi. Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun ní nítorí pé rúdurùdu yín ju ti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí i yín ká lọ, ati pé ẹ kò tẹ̀lé ìlànà mi, ẹ kò sì pa òfin mi mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀ ń tẹ̀lé ìlànà àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí i yín ká. Nítorí náà, èmi, OLUWA Ọlọrun fúnra mi, ni mo dójú le yín, n óo sì ṣe ìdájọ́ fun yín lójú àwọn orílẹ̀-èdè. Nítorí gbogbo ìwà ìríra yín, n óo ṣe ohun tí n kò ṣe rí si yín, tí n kò sì ní ṣe irú rẹ̀ mọ́ lae. Baba yóo máa pa ọmọ wọn jẹ láàrin yín; ọmọ yóo sì máa pa àwọn baba jẹ. N óo dájọ́ fun yín, n óo fọ́n gbogbo àwọn tí ó kù ninu yín káàkiri igun mẹrẹẹrin ayé. “Bí mo ti wà láàyè, n óo pa yín run. N kò ní fojú fo ohunkohun, n kò sì ní ṣàánú yín rárá; nítorí ẹ ti fi àwọn nǹkan ẹ̀sìn ìríra ati àṣà burúkú yín sọ ilé mímọ́ mi di aláìmọ́. Àjàkálẹ̀ àrùn ati ìyàn yóo pa ìdámẹ́ta lára yín, ogun tí yóo máa jà káàkiri yóo pa ìdámẹ́ta yín, n óo fọ́n ìdámẹ́ta yòókù káàkiri gbogbo ayé, n óo sì gbógun tì wọ́n. “Bẹ́ẹ̀ ni inú mi yóo ṣe máa ru si yín, tí n óo sì bínú si yín títí n óo fi tẹ́ ara mi lọ́rùn. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo sọ̀rọ̀ pẹlu owú nígbà tí mo bá bínú si yín tẹ́rùn. N óo sọ yín di ahoro ati ohun ẹ̀sín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yi yín ká ati lójú gbogbo àwọn tí wọn ń rékọjá lọ. “Ẹ óo di ẹni ẹ̀sín ati ẹni ẹ̀gàn, ẹni àríkọ́gbọ́n ati ẹni àríbẹ̀rù fún àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n yi yín ká; nígbà tí mo bá fi ibinu ati ìrúnú dájọ́ fun yín, tí mo sì jẹ yín níyà pẹlu ibinu. Nígbà tí mo bá ta ọfà burúkú mi si yín: ọfà ìyàn ati ọfà ìparun, tí n óo ta lù yín láti pa yín run, ìyàn óo mú lọpọlọpọ nígbà tí mo bá mú kí oúnjẹ yín tán pátá. N óo rán ìyàn ati àwọn ẹranko burúkú si yín, wọn óo sì pa yín lọ́mọ. Àjàkálẹ̀ àrùn ati ikú yóo bẹ́ sílẹ̀ láàrin yín, n óo sì jẹ́ kí ogun pa yín. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Ọmọ eniyan, dojú kọ àwọn òkè Israẹli kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí wọn. Sọ pé, ‘Ẹ̀yin òkè Israẹli, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA Ọlọrun wí. OLUWA Ọlọrun ń bá àwọn òkè ńláńlá ati àwọn òkè kéékèèké wí! Ó ń sọ fún àwọn ọ̀gbun ati àwọn àfonífojì pé, èmi fúnra mi ni n óo kó ogun wá ba yín, n óo sì pa àwọn ibi ìrúbọ yín run. Àwọn pẹpẹ ìrúbọ yín yóo di ahoro, a óo fọ́ àwọn pẹpẹ turari yín, n óo sì da òkú yín sílẹ̀ níwájú àwọn oriṣa yín. N óo da òkú ẹ̀yin ọmọ Israẹli sílẹ̀ níwájú àwọn oriṣa yín, n óo sì fọ́n egungun yín ká níbi pẹpẹ ìrúbọ yín. Ní ibikíbi tí ẹ bá ń gbé, àwọn ìlú yín yóo di ahoro, àwọn ibi ìrúbọ yín yóo di òkítì àlàpà, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn pẹpẹ oriṣa yín yóo di ahoro ati àlàpà. A óo fọ́ àwọn ère oriṣa yín, a óo pa wọ́n run, a óo wó pẹpẹ turari yín, iṣẹ́ yín yóo sì parẹ́. Òkú yóo sùn lọ bẹẹrẹ láàrin yín, ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA. “ ‘Sibẹsibẹ n óo dá díẹ̀ sí ninu yín; kí ẹ lè ní àwọn tí yóo bọ́ lọ́wọ́ ogun láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, nígbà tí ẹ bá fọ́n káàkiri ilé ayé. Nígbà náà, àwọn tí wọ́n sá àsálà ninu yín yóo ranti mi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí a bá kó wọn ní ìgbèkùn lọ, nígbà tí mo bá mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn wọn tí ó ń mú wọn kọ̀ mí sílẹ̀ kúrò, tí mo bá sì fọ́ ojú tí wọ́n fi ń ṣe àgbèrè tẹ̀lé àwọn oriṣa wọn. Ojú ara wọn yóo tì wọ́n nítorí ibi tí wọ́n ṣe, ati nítorí gbogbo ìwà ìríra wọn. Wọn yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA, ati pé kì í ṣe pé mo sọ ọ́ ní ọ̀rọ̀ ẹnu lásán pé n óo ṣe wọ́n níbi.’ ” OLUWA Ọlọrun ní: “Ẹ káwọ́ lérí kí ẹ máa fi ẹsẹ̀ janlẹ̀, kí ẹ sì wí pé, ‘Háà! Ó mà ṣe o!’ Ogun ati ìyàn ati àjàkálẹ̀-àrùn ni yóo pa ilé Israẹli nítorí ìwà ìríra wọn. Àjàkálẹ̀-àrùn ni yóo pa àwọn tí wọ́n wà lókèèrè; idà yóo pa àwọn tí wọ́n wà nítòsí, ìyàn yóo sì pa àwọn yòókù tí ogun ati àjàkálẹ̀-àrùn bá dá sí. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lára wọn patapata. Ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí òkú wọn bá sùn lọ káàkiri láàrin àwọn ère oriṣa wọn yíká pẹpẹ ìrúbọ wọn, ní gbogbo ibi ìrúbọ ati lórí gbogbo òkè ńlá, lábẹ́ gbogbo igi tútù ati gbogbo igi oaku eléwé tútù; ní gbogbo ibi tí wọ́n ti ń rú ẹbọ olóòórùn dídùn sí àwọn oriṣa wọn. Ọwọ́ mi óo tẹ̀ wọ́n; n óo sọ ilẹ̀ wọn di ahoro ati òkítì àlàpà, ní gbogbo ibùgbé wọn, láti ibi aṣálẹ̀ títí dé Ribila. Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.” OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun sọ nípa ilẹ̀ Israẹli ni pé: òpin ti dé. Òpin dé sórí igun mẹrẹẹrin ilẹ̀ náà. “Òpin ti dé ba yín báyìí, n óo bínú si yín, n óo da yín lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí ìwà yín; n óo sì jẹ yín níyà nítorí gbogbo ìwà ìríra yín. N kò ní fojú fo ọ̀rọ̀ yín, n kò sì ní ṣàánú yín. Ṣugbọn n óo jẹ yín níyà fún gbogbo ìwà yín níwọ̀n ìgbà tí ohun ìríra ṣì wà láàrin yín. Ẹ óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.” OLUWA Ọlọrun ní: “Àjálù dé! Ẹ wò ó! Àjálù ń ré lu àjálù. Òpin dé! Òpin ti dé; ó ti dé ba yín. Ẹ wò ó! Ó ti dé. Ìparun ti dé ba yín, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ yìí. Àkókò tó, ọjọ́ ti súnmọ́lé, ọjọ́ ìdàrúdàpọ̀, tí kì í ṣe ọjọ́ ariwo ayọ̀ lórí àwọn òkè. “Ó yá tí n óo bínú si yín, tí inú mi óo ru si yín gidi. N óo da yín lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí ìwà yín, n óo sì jẹ yín níyà nítorí gbogbo ìwà ìríra yín. N kò ní fojú fo ọ̀rọ̀ yín, n kò ní ṣàánú yín. N óo jẹ yín níyà gẹ́gẹ́ bí ìwà yín, níwọ̀n ìgbà tí ohun ìríra ṣì wà láàrin yín. Ẹ óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi OLUWA, ni mò ń jẹ yín níyà.” Ọjọ́ pé. Ẹ wò ó! Ọjọ́ ti pé! Ìparun yín ti dé. Ìwà àìṣẹ̀tọ́ ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni ìgbéraga ń rúwé. Ìwà ipá hù, ó dàgbà, ó di ọ̀pá ìwà ibi; bí ẹ ti pọ̀ tó, ẹ kò ní ṣẹ́ku ẹyọ ẹnìkan, àtẹ̀yin ati àwọn ohun ìní yín, ati ọrọ̀ yín ati ògo yín. Àkókò tó; ọjọ́ náà sì ti dé tán, kí ẹni tí ń ra nǹkan má ṣe yọ̀; bẹ́ẹ̀ ni kí ẹni tí ń tà má sì banújẹ́, nítorí ibinu ti dé sórí gbogbo wọn. Ẹni tí ń tà kò ní sí láyé láti pada síbi ohun tí ó tà ní ìgbà ayé ẹni tí ó rà á. Nítorí ibinu ti dé sórí gbogbo wọn. Kò sì ní yipada, bẹ́ẹ̀ ni nítorí ẹ̀ṣẹ̀ olukuluku, ẹnikẹ́ni ninu wọn kò ní sí láàyè. Wọn óo fọn fèrè ogun, wọn óo múra ogun, ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò ní jáde lọ sójú ogun nítorí ibinu mi ti dé sórí gbogbo wọn. Ogun ń bẹ lóde; àjàkálẹ̀-àrùn ati ìyàn wà ninu ilé. Ẹni tí ó bá wà lóko yóo kú ikú ogun. Ìyàn ati àjàkálẹ̀-àrùn yóo pa ẹni tí ó bá wà ninu ìlú. Bí àwọn kan bá kù, tí wọn sá àsálà, wọn yóo dàbí àdàbà àfonífojì lórí àwọn òkè. Gbogbo wọn yóo máa sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn olukuluku yóo máa dárò nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ọwọ́ gbogbo wọ́n yóo rọ; orúnkún wọn kò ní lágbára. Wọn óo wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ìpayà óo sì bá wọn. Ojú óo ti gbogbo wọn; gbogbo wọn óo sì di apárí. Wọ́n óo fọ́n fadaka wọn dà sílẹ̀ láàrin ìgboro. Wúrà wọn yóo sì dàbí ohun àìmọ́. Fadaka ati wúrà wọn kò ní lè gbà wọ́n kalẹ̀ lọ́jọ́ ibinu OLUWA. Kò ní lè tẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní lè jẹ ẹ́ yó. Nítorí pé wúrà ati fadaka ló mú wọn dẹ́ṣẹ̀. Wọ́n ń lo ohun ọ̀ṣọ́ wọn dáradára fún ògo asán; òun ni wọ́n fi ń ṣe àwọn ère ati oriṣa wọn, àwọn ohun ìríra tí wọn ń bọ. Nítorí náà, OLUWA óo sọ wọ́n di ohun àìmọ́ fún wọn. OLUWA ní, “N óo sọ wọ́n di ìjẹ fún àwọn àjèjì, n óo sì fi wọ́n ṣe ìkógun fún àwọn eniyan burúkú ilé ayé. Wọn óo sọ wọ́n di ohun eléèérí. N óo mójú kúrò lọ́dọ̀ wọn, kí wọ́n lè sọ ibi dídára mi di eléèérí. Àwọn ọlọ́ṣà yóo wọnú rẹ̀, wọn yóo sì sọ ọ́ di eléèérí. “Nítorí pé ìpànìyàn kún ilẹ̀ náà, ìlú wọn sì kún fún ìwà ipá. N óo kó àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n burú jùlọ wá, wọn óo wá gba ilé wọn. N óo fi òpin sí ìgbéraga àwọn alágbára wọn, wọn yóo sì sọ àwọn ibi mímọ́ wọn di eléèérí. Nígbà tí ìrora bá dé, wọn yóo máa wá alaafia, ṣugbọn wọn kò ní rí i. Àjálù yóo máa yí lu àjálù, ọ̀rọ̀ àhesọ yóo máa gorí ara wọn. Wọn yóo máa wo ojú wolii fún ìran ṣugbọn kò ní sí, alufaa kò ní náání òfin mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí ìmọ̀ràn mọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn àgbààgbà. Ọba yóo máa ṣọ̀fọ̀; àwọn olórí yóo sì wà ninu ìdààmú; ọwọ́ àwọn eniyan yóo sì máa gbọ̀n nítorí ìpayà. N óo san ẹ̀san iṣẹ́ wọn fún wọn; n óo sì dá wọn lẹ́jọ́ bí àwọn náà tí ń dá àwọn ẹlòmíràn lẹ́jọ́. Wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” Ní ọjọ́ karun-un, oṣù kẹfa ọdún kẹfa tí a ti wà ní ìgbèkùn, bí mo ti jókòó ninu ilé mi, tí àwọn àgbààgbà Juda sì jókòó níwájú mi, agbára OLUWA Ọlọrun bà lé mi níbẹ̀. Nígbà tí mo wò, mo rí nǹkankan tí ó dàbí eniyan. Láti ibi tí ó dàbí ìbàdí rẹ̀ dé ilẹ̀ jẹ́ iná, ibi ìbàdí rẹ̀ sókè ń kọ mànàmànà bí idẹ dídán. Ó na nǹkankan tí ó dàbí ọwọ́, ó fi gbá ìdí irun orí mi mú, ẹ̀mí sì gbé mi sókè sí agbede meji ọ̀run ati ayé, ó gbé mi lọ sí Jerusalẹmu, ninu ìran Ọlọrun, ó gbé mi sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá gbọ̀ngàn ti inú tí ó kọjú sí ìhà àríwá, níbi tí wọ́n gbé ère tí ń múni jowú sí. Mo rí ìfarahàn ògo Ọlọrun Israẹli níbẹ̀ bí mo ti rí i lákọ̀ọ́kọ́ ní àfonífojì. Ó bá sọ fún mi, pé: “Ọmọ eniyan, gbójú sókè sí apá àríwá.” Mo bá gbójú sókè sí apá àríwá. Wò ó! Mo rí ère kan tí ń múni jowú ní ìhà àríwá ẹnu ọ̀nà pẹpẹ ìrúbọ. OLUWA sọ fún mi pé: “Ọmọ eniyan, ṣé o rí ohun tí wọn ń ṣe? Ṣé o rí nǹkan ìríra ńlá tí àwọn ọmọ Israẹli ń ṣe níhìn-ín láti lé mi jìnnà sí ilé mímọ́ mi? N óo fi nǹkan ìríra ńlá mìíràn hàn ọ́.” OLUWA bá tún gbé mi lọ sí ẹnu ọ̀nà gbọ̀ngàn, nígbà tí mo wò yíká, mo rí ihò kan lára ògiri. Ó bá sọ fún mi pé, “Ọmọ eniyan, gbẹ́ ara ògiri yìí.” Nígbà tí mo gbẹ́ ara ògiri náà, mo rí ìlẹ̀kùn kan! Ó bá sọ fún mi pé, “Wọlé kí o rí nǹkan ìríra tí wọn ń ṣe níbẹ̀.” Mo bá wọlé láti wo ohun tí ó wà níbẹ̀. Mo rí àwòrán oríṣìíríṣìí kòkòrò ati ti ẹranko, tí ń rí ni lára, ati gbogbo oriṣa àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n yà sí ara ògiri yíká. Mo sì rí aadọrin ninu àwọn àgbààgbà àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n dúró níwájú àwọn oriṣa wọnyi, Jaasanaya ọmọ Ṣafani dúró láàrin wọn. Olukuluku mú ohun tí ó fi ń sun turari lọ́wọ́, èéfín turari sì ń fẹ́ lọ sókè. OLUWA tún bi mí pé: “Ọmọ eniyan, ṣé o rí ohun tí àwọn àgbààgbà ilé Israẹli ń ṣe ninu òkùnkùn? Ṣé o rí ohun tí olukuluku ń ṣe ninu yàrá tí ó kún fún àwòrán ère oriṣa? Wọ́n ń wí pé, ‘OLUWA kò rí wa, ó ti kọ ilẹ̀ wa sílẹ̀.’ ” Ó tún sọ fún mi pé, “N óo fi nǹkan ìríra ńlá mìíràn tí ó jù báyìí lọ tí wọn ń ṣe hàn ọ́.” Nígbà náà ni ó mú mi lọ sí ẹnu ọ̀nà tí ó wà ní ìhà àríwá ilé OLUWA. Wò ó, mo rí àwọn obinrin kan níbẹ̀, tí wọ́n jókòó, tí wọn ń sunkún nítorí Tamusi. Ó sì bi mí pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, ǹjẹ́ o rí ohun tí wọn ń ṣe yìí? O óo tún rí nǹkan ìríra tí ó ju èyí lọ.” Ó mú mi wọ inú gbọ̀ngàn tí ó wà ninu ilé OLUWA; mo bá rí àwọn ọkunrin mẹẹdọgbọn kan, wọ́n dúró lẹ́nu ọ̀nà tẹmpili ilé OLUWA, láàrin ìloro ati pẹpẹ. Wọ́n kẹ̀yìn sí tẹmpili OLUWA, wọ́n sì kọjú sí ìlà oòrùn. Wọ́n ń foríbalẹ̀ wọ́n ń bọ oòrùn. Ó bi mí pé: “Ọmọ eniyan, ṣé o rí ohun tí wọn ń ṣe yìí? Ṣé nǹkan ìríra tí àwọn ọmọ ilé Juda ń ṣe níhìn-ín kò jọ wọ́n lójú ni wọ́n ṣe mú kí ìwà ìkà kún ilẹ̀ yìí, tí wọn ń mú mi bínú sí i? Wò bí wọ́n ti ń tàbùkù mi, tí wọn ń fín mi níràn. Nítorí náà, n óo bínú sí wọn, n kò ní fojú fo iṣẹ́ wọn, n kò sì ní ṣàánú wọn. Wọ́n ìbáà máa kígbe sí mi létí, n kò ní dá wọn lóhùn.” Lẹ́yìn náà, Ọlọrun kígbe sí mi létí, ó ní, “Ẹ súnmọ́bí, ẹ̀yin tí ẹ óo pa ìlú yìí run, kí olukuluku mú nǹkan ìjà rẹ̀ lọ́wọ́.” Wò ó! Mo bá rí àwọn ọkunrin mẹfa kan tí wọn ń bọ̀ láti ẹnu ọ̀nà òkè tí ó kọjú sí ìhà àríwá. Olukuluku mú ohun ìjà tí ó fẹ́ fi pa eniyan lọ́wọ́. Ọkunrin kan wà láàrin wọn tí ó wọ aṣọ funfun, ó sì ní àpótí ìkọ̀wé kan lẹ́gbẹ̀ẹ́. Wọ́n wọlé, wọ́n dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ idẹ. Ògo Ọlọrun Israẹli ti gbéra kúrò lórí àwọn Kerubu tí ó wà, ó dúró sí àbáwọlé. Ó ké sí ọkunrin tí ó wọ aṣọ funfun náà, tí ó sì ní àpótí ìkọ̀wé kan lẹ́gbẹ̀ẹ́. OLUWA bá sọ fún un pé, “Lọ káàkiri ìlú Jerusalẹmu, kí o fi àmì sí iwájú àwọn eniyan tí wọ́n bá ń kẹ́dùn, tí gbogbo nǹkan ìríra tí àwọn eniyan ń ṣe láàrin ìlú náà sì dùn wọ́n dọ́kàn.” Mo sì gbọ́ tí ó wí fún àwọn yòókù pé: “Ẹ lọ káàkiri ìlú yìí, kí ẹ máa pa àwọn eniyan. Ẹ kò gbọdọ̀ dá ẹnikẹ́ni sí, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣàánú ẹnikẹ́ni. Ẹ pa àwọn àgbàlagbà patapata, ati àwọn ọdọmọkunrin ati ọdọmọbinrin pẹlu, ati àwọn ọmọde ati àwọn obinrin. Ṣugbọn ẹ má fọwọ́ kan ẹnikẹ́ni tí àmì bá wà níwájú rẹ̀. Ẹ bẹ̀rẹ̀ láti ibi mímọ́ mi.” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ pẹlu àwọn àgbààgbà tí wọ́n wà níwájú ilé OLUWA. Lẹ́yìn náà, Ọlọrun sọ fún wọn pé: “Ẹ sọ ilé náà di aláìmọ́, ẹ kó òkú eniyan kún gbọ̀ngàn rẹ̀, kí ẹ sì bọ́ síta.” Wọ́n bá bẹ́ sí ìgboro, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí pa àwọn eniyan láàrin ìlú. Bí wọ́n ti ń pa àwọn eniyan, tí èmi nìkan dá dúró, mo dojúbolẹ̀, mo kígbe. Mo ní, “Áà! OLUWA Ọlọrun, ṣé o óo pa gbogbo àwọn tí wọ́n kù ní Israẹli nítorí pé ò ń bínú sí Jerusalẹmu ni?” Ó dá mi lóhùn, ó ní: “Ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli ati ti Juda pọ̀jù. Ilẹ̀ náà kún fún ìpànìyàn, ìlú yìí sì kún fún ìwà àìṣẹ̀tọ́. Wọ́n ń wí pé, ‘OLUWA ti kọ ilẹ̀ yìí sílẹ̀, kò sì rí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ninu rẹ̀.’ N kò ní mójú fo ọ̀rọ̀ wọn, n kò sì ní ṣàánú wọn. N óo da ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wọn lé wọn lórí.” Mo bá gbọ́ tí ọkunrin tí ó wọ aṣọ funfun, tí ó sì ní àpótí ìkọ̀wé lẹ́gbẹ̀ẹ́, ń jábọ̀ pé, “Mo ti ṣe bí o ti pàṣẹ fún mi.” Lẹ́yìn náà, mo wo orí àwọn Kerubu, mo rí kinní kan róbótó róbótó, wọ́n dàbí òkúta safire, ìrísí wọn dàbí ìtẹ́. Ọlọrun bá sọ fún ọkunrin tí ó wọ aṣọ funfun náà pé, “Bọ́ sí ààrin àwọn àgbá tí wọn ń yí, tí wọ́n wà lábẹ́ àwọn Kerubu. Bu ẹ̀yinná tí ó wà láàrin wọn kún ọwọ́ rẹ, kí o sì fọ́n ọn sórí ìlú yìí káàkiri.” Mo bá rí i tí ó wọlé lọ. Ìhà gúsù ilé náà ni àwọn Kerubu dúró sí nígbà tí ọkunrin náà wọlé, ìkùukùu sì bo àgbàlá ààrin ilé náà. Ìfarahàn ògo OLUWA gbéra kúrò lórí àwọn Kerubu, ó lọ dúró sí àbáwọlé. Ìkùukùu kún gbogbo inú ilé náà, ìmọ́lẹ̀ ògo OLUWA sì kún gbogbo inú àgbàlá. Ariwo ìyẹ́ àwọn Kerubu náà dé àgbàlá òde. Ó dàbí ìgbà tí Ọlọrun Olodumare bá ń sọ̀rọ̀. Nígbà tí OLUWA pàṣẹ fún ọkunrin tí ó wọ aṣọ funfun náà pé kí ó mú iná láàrin àwọn àgbá tí ń yí, tí ó wà láàrin àwọn Kerubu, ọkunrin náà wọlé, ó lọ dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ àgbá náà. Ọ̀kan lára àwọn Kerubu náà na ọwọ́ sí inú iná tí ó wà láàrin wọn, ó bù ú sí ọwọ́ ọkunrin aláṣọ funfun náà. Ọkunrin náà gbà á, ó sì jáde. Ó dàbí ẹni pé àwọn Kerubu náà ní ọwọ́ bíi ti eniyan lábẹ́ ìyẹ́ wọn. Mo wòye, mo sì rí i pé àgbá mẹrin ni ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn Kerubu náà: àgbá kọ̀ọ̀kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Kerubu kọ̀ọ̀kan. Àwọn kẹ̀kẹ́ náà ń dán yinrinyinrin bí òkúta Kirisolite. Àwọn mẹrẹẹrin rí bákan náà, ó sì dàbí ìgbà tí àwọn àgbá náà wọnú ara wọn. Bí wọn tí ń lọ, ibikíbi tí ó bá wu àwọn Kerubu náà ninu ẹ̀gbẹ́ mẹrẹẹrin tí wọ́n kọjú sí ni wọ́n lè lọ láì jẹ́ pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yí ojú pada, nítorí pé ibikíbi tí èyí tí ó wà níwájú bá kọjú sí ni àwọn yòókù máa ń lọ. Gbogbo ara wọn àtẹ̀yìn wọn, àtọwọ́, àtìyẹ́ ati gbogbo ẹ̀gbẹ́ kẹ̀kẹ́ wọn kún fún ojú. Mo gbọ́ tí wọ́n pe àwọn àgbá náà ní àgbá tí ń sáré yí. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu wọn ní iwájú mẹrin mẹrin. Iwájú kinni jẹ́ iwájú Kerubu, ekeji jẹ́ iwájú eniyan, ẹkẹta jẹ́ iwájú kinniun, ẹkẹrin sì jẹ́ iwájú ẹyẹ idì. Àwọn Kerubu náà bá gbéra nílẹ̀, àwọn ni ẹ̀dá alààyè tí mo rí ní etí odò Kebari. Bí wọn tí ń lọ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbá náà ń lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn. Bí àwọn Kerubu náà bá fẹ́ fò, tí wọ́n bá na ìyẹ́ apá wọn, àwọn àgbá náà kìí kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn. Bí wọn bá dúró, àwọn náà á dúró. Bí wọn bá gbéra nílẹ̀, àwọn náà á gbéra, nítorí pé ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè náà wà ninu wọn. Ìtànṣán ògo OLUWA jáde kúrò ní àbáwọlé, ó sì dúró sí orí àwọn Kerubu náà. Àwọn Kerubu bá na ìyẹ́ apá wọn, wọ́n gbéra nílẹ̀ lójú mi, bí wọ́n ti ń lọ, àwọn àgbá náà wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn. Wọ́n dúró lẹ́nu ọ̀nà ilé OLUWA tí ó kọjú sí ìhà ìlà oòrùn, ìtànṣán ògo Ọlọrun Israẹli sì wà lórí wọn. Àwọn wọnyi ni àwọn ẹ̀dá alààyè tí mo rí lábẹ́ Ọlọrun Israẹli ní etí odò Kebari. Mo sì mọ̀ pé Kerubu ni wọ́n. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní iwájú mẹrin mẹrin ati ìyẹ́ mẹrin mẹrin, wọ́n sì ní ọwọ́ bí ọwọ́ eniyan lábẹ́ ìyẹ́ wọn. Bí iwájú àwọn tí mo rí lẹ́bàá odò Kebari ti rí gan-an ni iwájú wọn rí. Olukuluku ń rìn lọ siwaju tààrà. Ẹ̀mí gbé mi lọ sí ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA tí ó kọjú sí ìhà ìlà oòrùn. Àwọn ọkunrin mẹẹdọgbọn kan wà lẹ́nu ọ̀nà náà, mo rí i pé àwọn meji láàrin wọn jẹ́ ìjòyè: Jaasanaya, ọmọ Aṣuri, ati Pelataya, ọmọ Bẹnaya. OLUWA sọ fún mi, pé, “Ìwọ Ọmọ eniyan, àwọn tí wọn ń gbèrò ibi nìyí; tí wọn ń fún àwọn eniyan ìlú yìí ní ìmọ̀ràn burúkú. Wọ́n ń wí pé, ‘àkókò ilé kíkọ́ kò tíì tó. Ìlú yìí dàbí ìkòkò, àwa sì dàbí ẹran.’ Nítorí náà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ burúkú nípa wọn, ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀.” Ẹ̀mí OLUWA bá bà lé mi, ó sọ fún mi, pé, “OLUWA ní, Èrò yín nìyí, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, mo mọ ohun tí ẹ̀ ń rò lọ́kàn, Ẹ ti pa ọpọlọpọ eniyan ní ààrin ìlú yìí; ẹ sì ti da òkú wọn kún gbogbo ìgboro ati òpópónà ìlú. “Nítorí náà, àwọn òkú yín tí ẹ dà sí ààrin ìlú yìí ni ẹran, ìlú yìí sì ni ìkòkò, ṣugbọn n óo mu yín kúrò láàrin rẹ̀. Idà ni ẹ̀ ń bẹ̀rù, idà náà ni n óo sì jẹ́ kí ó pa yín. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo wí bẹ́ẹ̀. N óo ko yín kúrò ninu ìlú yìí, n óo sì ko yín lé àwọn àjèjì lọ́wọ́. N óo sì ṣe ìdájọ́ yín. Idà yóo pa yín, ààlà ilẹ̀ Israẹli ni n óo ti ṣe ìdájọ́ yín; ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA. Ìlú yìí kò ní jẹ́ ìkòkò fun yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní jẹ́ ẹran ninu rẹ̀; ní ààlà ilẹ̀ Israẹli ni n óo ti ṣe ìdájọ́ yín. Ẹ óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA; nítorí pé ẹ kò rìn ninu ìlànà mi, ẹ kò sì pa òfin mi mọ́, ṣugbọn ẹ ti gba àṣà àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n yi yín ká.” Bí mo tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ ni Pelataya, ọmọ Bẹnaya, bá kú. Mo bá dojúbolẹ̀, mo kígbe sókè, mo ní, “Áà! OLUWA Ọlọrun, ṣé o fẹ́ pa àwọn ọmọ Israẹli yòókù tán ni?” OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, gbogbo àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu, ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn arakunrin wọn, tí ẹ jọ wà ní ìgbèkùn, àní gbogbo ilé Israẹli; wọ́n ń sọ pé, ‘Wọ́n ti lọ jìnnà kúrò lọ́dọ̀ OLUWA, OLUWA sì ti fún wa ní ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ohun ìní.’ “Nítorí náà wí fún wọn pé èmi, OLUWA Ọlọrun ní, bí mo tilẹ̀ kó wọn lọ jìnnà sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, tí mo sì fọ́n wọn káàkiri ilẹ̀ ayé, sibẹsibẹ mo jẹ́ ibi mímọ́ fún wọn fún ìgbà díẹ̀ ní ilẹ̀ tí wọ́n lọ. “Nítorí náà, wí fún wọn pé èmi, ‘OLUWA Ọlọrun ní n óo kó wọn jọ láti ààrin àwọn ẹ̀yà ati orílẹ̀-èdè mìíràn tí mo fọ́n wọn ká sí, n óo sì fún wọn ní ilẹ̀ Israẹli.’ Nígbà tí wọ́n bá dé ibẹ̀, wọn óo ṣa gbogbo ohun ẹ̀gbin ati ìríra rẹ̀ kúrò ninu rẹ̀. Ó ní, mo sọ pé, n óo fún wọn ní ọkàn kan, n óo fi ẹ̀mí titun sí wọn ninu. N óo yọ ọkàn òkúta kúrò láyà wọn, n óo sì fún wọn ní ọkàn ẹran; kí wọ́n lè máa rìn ninu ìlànà mi, kí wọ́n sì lè máa pa òfin mi mọ́. Wọn óo jẹ́ eniyan mi, èmi náà óo sì jẹ́ Ọlọrun wọn. Ṣugbọn n óo fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ jẹ àwọn tí ọkàn wọn ń fà sí àwọn ohun ẹ̀gbin ati ìríra. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” Lẹ́yìn náà, àwọn Kerubu bá gbéra, wọ́n fò, pẹlu àgbá, ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ wọn; ìtànṣán ògo OLUWA Ọlọrun Israẹli sì wà lórí wọn. Ògo OLUWA gbéra kúrò láàrin ìlú náà, ó sì dúró sórí òkè tí ó wà ní apá ìhà ìlà oòrùn ìlú náà. Ẹ̀mí bá gbé mi sókè ní ojúran, ó gbé mi wá sí ilẹ̀ àwọn ará Kalidea, lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèkùn. Lẹ́yìn náà, ìran tí mo rí bá kúrò lójú mi. Mo sì sọ gbogbo ohun tí OLUWA fihàn mí fún àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèkùn. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, ààrin àwọn olóríkunkun ni o wà: àwọn tí wọ́n ní ojú, ṣugbọn tí wọn kò fi ríran. Wọ́n ní etí, ṣugbọn wọn kò fi gbọ́ràn, nítorí pé ọmọ ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n. “Nítorí náà, ìwọ ọmọ eniyan, di ẹrù rẹ bíi ti ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn, kí o sì jáde ní ìlú lọ́sàn-án gangan níṣojú wọn. Lọ láti ilé rẹ sí ibòmíràn bí ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn. Bóyá yóo yé wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n. Kó ẹrù rẹ jáde lójú wọn ní ọ̀sán gangan kí ìwọ pàápàá jáde lójú wọn ní ìrọ̀lẹ́ bí ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn. Dá odi ìlú lu níṣojú wọn, kí o sì gba ibẹ̀ jáde. Gbé ẹrù rẹ lé èjìká níṣojú wọn, kí o sì jáde ní òru. Fi nǹkan bojú rẹ kí o má baà rí ilẹ̀, nítorí pé ìwọ ni mo ti fi ṣe àmì fún ilé Israẹli.” Mo ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ fún mi. Mo gbé ẹrù mi jáde lọ́sàn-án gangan bí ẹrù ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, mo fi ọwọ́ ara mi dá odi ìlú lu, mo sì gba ibẹ̀ jáde lóru. Mo gbé ẹrù mi lé èjìká níṣojú wọn. Ní òwúrọ̀, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, ǹjẹ́ àwọn ọmọ Israẹli, àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọnyi kò bèèrè lọ́wọ́ rẹ pé kí ni ò ń ṣe? Wí fún wọn pé, ‘Èmi OLUWA Ọlọrun sọ pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń bá àwọn olórí Jerusalẹmu ati àwọn eniyan Israẹli tí ó kù ninu rẹ̀ wí.’ Sọ fún wọn pé ó jẹ́ àpẹẹrẹ fún wọn. Bí o ti ṣe ni wọ́n óo ṣe wọ́n, wọn óo lọ sí ìgbèkùn. Ẹni tí ó jẹ́ olórí láàrin wọn yóo gbé ẹrù rẹ̀ lé èjìká ní alẹ́, yóo sì jáde kúrò nílùú. Yóo dá odi ìlú lu, yóo gba ibẹ̀ jáde. Yóo fi nǹkan bojú kí ó má ba à rí ilẹ̀. N óo na àwọ̀n mi lé e lórí, yóo sì kó sinu tàkúté tí mo dẹ sílẹ̀. N óo mú un lọ sí Babiloni ní ilẹ̀ àwọn ará Kalidea. Kò ní fi ojú rí i, bẹ́ẹ̀ sì ni ibẹ̀ ni yóo kú sí. Gbogbo àwọn tí wọ́n yí i ká ni n óo túká: gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ni n óo sì jẹ́ kí ogun máa lé lọ. “Wọn óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA, nígbà tí mo bá fọ́n wọn ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, tí mo tú wọn ká sórí ilẹ̀ ayé. N óo jẹ́ kí díẹ̀ ninu wọn bọ́ lọ́wọ́ ogun, ati ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn, kí wọ́n lè ròyìn gbogbo ohun ìríra wọn láàrin àwọn tí wọn óo lọ máa gbé; wọn óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, máa jẹun. Bí o tí ń jẹun lọ́wọ́, jẹ́ kí ọwọ́ rẹ máa gbọ̀n, kí o sì máa fi ìwárìrì ati ìbẹ̀rù mu omi rẹ. Kí o wá sọ fún àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà pé, ‘OLUWA Ọlọrun sọ nípa àwọn ará Jerusalẹmu ati àwọn tí ń gbé ilẹ̀ Israẹli pé: Pẹlu ìpayà ni wọn óo máa fi jẹun, tí wọn óo sì máa fi mu omi, nítorí pé ilẹ̀ wọn yóo di ahoro nítorí ìwà ipá tí àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ ń hù. Àwọn ìlú tí eniyan ń gbé yóo di òkítì àlàpà, gbogbo ilẹ̀ náà yóo di ahoro. Ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’ ” OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, kí ló dé tí wọ́n máa ń pòwe ní ilẹ̀ Israẹli pé, ‘Ọjọ́ ń pẹ́ sí i, gbogbo ìran tí àwọn aríran rí sì já sí òfo.’ Nítorí náà, sọ fún wọn pé èmi, OLUWA Ọlọrun ní: ‘N óo fi òpin sí òwe yìí, wọn kò ní pa á ní ilẹ̀ Israẹli mọ́.’ Sọ fún wọn pé: Ọjọ́ ń súnmọ́lé tí gbogbo ìran àwọn aríran yóo ṣẹ. “Nítorí pé ìran irọ́ tabi àfọ̀ṣẹ ẹ̀tàn yóo dópin láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Ṣugbọn èmi OLUWA yóo sọ ohun tí mo bá fẹ́ sọ, yóo sì ṣẹ. Kò ní falẹ̀ mọ́, ṣugbọn níṣojú ẹ̀yin ìdílé ọlọ̀tẹ̀, ni n óo sọ̀rọ̀, tí n óo sì mú un ṣẹ. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo wí bẹ́ẹ̀.” OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, gbọ́ bí àwọn ọmọ Israẹli ti ń wí pé, Ìran ọjọ́ iwájú ni ò ń rí, o sì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ gbọọrọ. Nítorí náà, wí fún wọn pé: mo ní n kò ní fi ọ̀rọ̀ mi falẹ̀ mọ́, ṣugbọn ohun tí mo bá sọ yóo ṣẹ. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo wí bẹ́ẹ̀.” OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún àwọn wolii Israẹli. Sọ àsọtẹ́lẹ̀, kí o sì wí fún àwọn tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ti ara wọn pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA!’ ” OLUWA Ọlọrun ní, “Ègbé ni fún àwọn òmùgọ̀ wolii tí wọn ń tẹ̀lé ìmọ̀ ara wọn láì jẹ́ pé wọ́n ríran rárá. Israẹli, àwọn wolii rẹ dàbí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ láàrin òkítì àlàpà. Wọn kò gun ibi tí odi ti lanu lọ, kí wọn tún un mọ yípo agbo ilé Israẹli, kí ó má baà wó lulẹ̀ lọ́jọ́ ìdájọ́ OLUWA. Wọ́n ń sọ̀rọ̀ èké, wọ́n ń woṣẹ́ irọ́, wọ́n ń wí pé, ‘OLUWA wí báyìí.’ Bẹ́ẹ̀ sì ni OLUWA kò rán wọn níṣẹ́ kankan; sibẹ wọ́n ń retí pé kí OLUWA mú ọ̀rọ̀ wọn ṣẹ. Ǹjẹ́ ìran èké kọ́ ni wọ́n ń rí, tí wọ́n sì ń woṣẹ́ irọ́, nígbàkúùgbà tí wọn bá wí pé, ‘OLUWA wí báyìí’, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò sọ̀rọ̀?” Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “Nítorí ọ̀rọ̀ asán tí ẹ̀ ń sọ, ati ìran èké tí ẹ̀ ń rí, mo lòdì si yín. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA Ọlọrun sọ. N óo jẹ àwọn wolii tí wọn ń ríran èké níyà ati àwọn tí wọn ń woṣẹ́ irọ́. Wọn kò ní bá àwọn eniyan mi péjọ mọ́, tabi kí á kọ orúkọ wọn mọ́ ilé Israẹli, tabi kí wọ́n wọ ilẹ̀ Israẹli mọ́. Ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun. “Nítorí pé wọ́n ti ṣi àwọn eniyan mi lọ́nà wọ́n ń wí fún wọn pé, ‘Alaafia’ nígbà tí kò sí alaafia. Ati pé nígbà tí àwọn eniyan mi ń mọ odi, àwọn wolii wọnyi ń kùn ún ní ọ̀dà funfun. Wí fún àwọn tí wọn ń kun odi náà ní ọ̀dà pé, òjò ńlá ń bọ̀, yìnyín ńlá yóo bọ́, ìjì líle yóo jà. Nígbà tí odi náà bá wó, ǹjẹ́ àwọn eniyan kò ní bi yín pé, ‘Ọ̀dà funfun tí ẹ fi ń kun ara rẹ̀ ńkọ́?’ ” Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “N óo fi ibinu mú kí ìjì líle jà, n óo fi ìrúnú rọ ọ̀wààrà òjò ńlá, n óo mú kí yìnyín ńláńlá bọ́ kí ó pa á run. N óo wó ògiri tí ẹ kùn lẹ́fun, n óo wó o lulẹ̀ débi pé ìpìlẹ̀ rẹ̀ yóo hàn síta. Nígbà tí ó bá wó, ẹ óo ṣègbé ninu rẹ̀. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA. “Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lára odi náà ati àwọn tí wọn ń kùn ún lẹ́fun. N óo wí fun yín pé, odi kò sí mọ́, àwọn tí wọn ń kùn ún lẹ́fun náà kò sì sí mọ́; àwọn wolii Israẹli tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jerusalẹmu tí wọn ń ríran alaafia nípa rẹ̀, nígbà tí kò sí alaafia. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA Ọlọrun wí.” OLUWA ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, dojú kọ àwọn ọmọbinrin àwọn eniyan rẹ, tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ti ọkàn wọn. Sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wọn, kí o wí pé èmi OLUWA Ọlọrun sọ pé, ‘Ègbé ni fún àwọn obinrin tí wọn ń so ẹ̀gbà òògùn mọ́ gbogbo eniyan lọ́wọ́, tí wọ́n sì ń ṣe ìbòjú fún gbogbo eniyan, kí ọwọ́ wọn lè ká eniyan. Ṣé ẹ̀ ń dọdẹ ẹ̀mí àwọn eniyan mi ni, kí ẹ lè dá àwọn ẹlòmíràn sí fún èrè ara yín? Ẹ ti sọ mí di ẹni ìríra lójú àwọn eniyan mi nítorí ẹ̀kún ọwọ́ ọkà baali mélòó kan ati èérún burẹdi. Ẹ̀ ń pa àwọn tí kò yẹ kí ẹ pa, ẹ sì ń dá àwọn tí kò yẹ kí wọ́n wà láàyè sí, nípa irọ́ tí ẹ̀ ń pa fún àwọn eniyan mi, tí wọn ń fetí sí irọ́ yín.’ “Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Mo kórìíra àwọn ẹ̀gbà ọwọ́, òògùn tí ẹ fi ń dọdẹ ẹ̀mí eniyan. N óo já wọn kúrò lápá yín, n óo sì tú àwọn ẹ̀mí tí ẹ dè sílẹ̀ bí ẹyẹ. N óo ya ìbòjú yín kúrò, n óo gba àwọn eniyan mi lọ́wọ́ yín. Wọn kò ní jẹ́ ohun ọdẹ lọ́wọ́ yín mọ́, ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’ “Nítorí pé ẹ̀ ń fi àrékérekè ba àwọn olódodo lọ́kàn jẹ́, nígbà tí n kò fẹ́ bà wọ́n lọ́kàn jẹ́; ẹ sì ń ṣe onígbọ̀wọ́ àwọn eniyan burúkú kí wọn má baà yipada lọ́nà ibi wọn, kí wọn sì rí ìgbàlà. Nítorí náà, ẹ kò ní ríran èké mọ́, ẹ kò sì ní woṣẹ́ mọ́. N óo gba àwọn eniyan mi lọ́wọ́ yín, nígbà náà, ni ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” Àwọn àgbààgbà Israẹli kan tọ̀ mí wá, wọ́n jókòó siwaju mi. OLUWA bá bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, àwọn ọkunrin wọnyi kó oriṣa wọn lé ọkàn, wọ́n sì gbé ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tí ń múni kọsẹ̀ siwaju wọn. Ṣé wọ́n rò pé n óo dá wọn lóhùn tí wọ́n bá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ mi? “Nítorí náà, sọ fún wọn pé, èmi OLUWA Ọlọrun ní ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli tí ó bá kó oriṣa rẹ̀ lé ọkàn tí ó gbé ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tí ń múni kọsẹ̀ siwaju rẹ̀, tí ó wá tọ wolii wá, èmi OLUWA fúnra mi ni n óo dá a lóhùn gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ oriṣa rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe, kí n lè dá ọkàn àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ṣáko kúrò lọ́dọ̀ mi nítorí oriṣa wọn pada. “Nítorí náà, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé èmi OLUWA Ọlọrun ní kí wọn ronupiwada, kí wọn pada lẹ́yìn àwọn oriṣa wọn, kí wọn yíjú kúrò lára àwọn nǹkan ìríra tí wọn ń bọ “Nítorí pé bí ẹnikẹ́ni ninu ẹ̀yin ọmọ Israẹli tabi ninu àwọn àlejò tí wọ́n wọ̀ ní ilẹ̀ Israẹli bá ya ara rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ó Kó oriṣa rẹ̀ lé ọkàn, tí ó sì gbé ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tí ń múni kọsẹ̀ ka iwájú rẹ̀, tí ó wá tọ wolii lọ láti wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ ní orúkọ mi, èmi OLUWA fúnra mi ni n óo dá a lóhùn. N óo dójú lé olúwarẹ̀, n óo fi ṣe ẹni àríkọ́gbọ́n ati àmúpòwe. N óo pa á run láàrin àwọn eniyan mi; ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA. “Bí wolii kan bá jẹ́ kí á ṣi òun lọ́nà, tí ó sì sọ̀rọ̀, a jẹ́ pé èmi OLUWA ni mo jẹ́ kí wolii náà ṣìnà, N óo na ọwọ́ ìyà sí i, n óo sì pa á run kúrò láàrin àwọn ọmọ Israẹli, eniyan mi. Àwọn mejeeji yóo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Irú ìyà kan náà ni n óo fi jẹ wolii alára ati ẹni tí ó lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. N óo ṣe bẹ́ẹ̀, kí ẹ̀yin ọmọ Israẹli má baà ṣáko kúrò lọ́dọ̀ mi mọ́, tabi kí ẹ máa fi ẹ̀ṣẹ̀ sọ ara yín di aláìmọ́. Ṣugbọn kí ẹ lè jẹ́ eniyan mi, kí n sì jẹ́ Ọlọrun yín. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, bí orílẹ̀-èdè kan bá ṣẹ̀ mí, tí wọ́n ṣe aiṣootọ, tí mo bá run gbogbo oúnjẹ wọn, tí mo mú kí ìyàn jà ní ilẹ̀ náà, tí mo sì run ati eniyan ati ẹranko inú rẹ̀, bí àwọn ọkunrin mẹta wọnyi: Noa, Daniẹli ati Jobu bá tilẹ̀ wà ninu rẹ̀, ẹ̀mí wọn nìkan ni wọn óo lè fi òdodo wọn gbàlà. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “Bí mo bá jẹ́ kí àwọn ẹranko burúkú já wọ orílẹ̀-èdè náà, kí wọ́n pa wọ́n lọ́mọ jẹ, tí wọ́n sọ ilẹ̀ náà di ahoro, tí ẹnikẹ́ni kò lè gba ibẹ̀ kọjá mọ́, nítorí àwọn ẹranko tí wọ́n wà níbẹ̀, bí Noa, ati Daniẹli ati Jobu bá tilẹ̀ wà níbẹ̀, bí èmi OLUWA Ọlọrun fi ara mi búra pé, wọn kò ní lè gba ọmọkunrin tabi ọmọbinrin wọn là. Ara wọn nìkan ni wọn yóo lè gbàlà, ilẹ̀ náà yóo sì di ahoro. Bí mo bá mú kí ogun jà ní ilẹ̀ náà, tí mo sì pa eniyan ati ẹranko run ninu rẹ̀, bí àwọn ọkunrin mẹta náà bá tilẹ̀ wà níbẹ̀, bí èmi OLUWA ti wà láàyè, wọn kò ní lè gba ọmọkunrin tabi ọmọbinrin wọn là. Ara wọn nìkan ni wọn yóo lè gbàlà. “Tabi bí mo bá rán àjàkálẹ̀ àrùn sí orílẹ̀-èdè náà, tí mo sì fi ibinu bá a jà, débi pé eniyan kú níbẹ̀, tí mo pa ati eniyan ati ẹranko run ninu rẹ̀, bí Noa, Daniẹli ati Jobu bá tilẹ̀ wà níbẹ̀, èmi OLUWA Ọlọrun fi ara mi búra pé, wọn kò ní lè gba ọmọkunrin tabi ọmọbinrin wọn là. Ara wọn nìkan ni wọn yóo lè fi òdodo wọn gbàlà.” Nítorí OLUWA Ọlọrun ní, “Báwo ni yóo ti wá burú tó nisinsinyii tí mo rán ìjẹníyà burúkú mẹrin wọnyi sí Jerusalẹmu: ogun, ìyàn, ẹranko burúkú ati àjàkálẹ̀ àrùn láti pa eniyan ati ẹranko run ninu rẹ̀. Sibẹ bí a bá rí àwọn tí wọ́n yè ninu wọn lọkunrin ati lobinrin, tí wọ́n bá wá sọ́dọ̀ rẹ, tí o rí ìwà ati ìṣe wọn, o óo gbà pé mo jàre ní ti ibi tí mo jẹ́ kí ó ṣẹlẹ̀ sí Jerusalẹmu. Wọn yóo jẹ́ ìtùnú fún ọ nígbà tí o bá rí ìwà ati ìṣe wọn, O óo sì mọ̀ pé bí kò bá nídìí, n kò ní ṣe gbogbo ohun tí mo ṣe sí wọn. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, ọ̀nà wo ni ẹ̀ka igi àjàrà gbà dára ju ẹ̀ka igi yòókù lọ; àní igi àjàrà tí ó wà láàrin àwọn igi inú igbó? Ǹjẹ́ ẹnìkan a máa fi igi rẹ̀ ṣe ohunkohun? Àbí wọn a máa gé lára rẹ̀ kí wọn fi gbẹ́ èèkàn tí wọ́n fi ń so nǹkan mọ́lẹ̀? Iná ni wọ́n ń fi í dá, nígbà tí iná bá jó o lórí, tí ó jó o nídìí, tí ó sì sọ ààrin rẹ̀ di èédú, ṣé ó tún ṣe é fi ṣe ohunkohun? Nígbà tí ó wà ní odidi, kò wúlò fún nǹkankan. Nígbà tí iná ti jó o, tí ó ti di èédú, ṣé eniyan tún lè fi ṣe ohunkohun?” Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “Bí ẹ̀ka àjàrà tí mo sọ di igi ìdáná láàrin àwọn igi, bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu. N óo dójú lé wọn, bí wọn tilẹ̀ yọ jáde ninu iná, sibẹsibẹ iná ni yóo jó wọn. Nígbà tí mo bá dójú lé wọn, ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA. N óo sọ ilẹ̀ náà di ahoro nítorí pé wọ́n ti hùwà aiṣootọ. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, fi nǹkan ìríra tí Jerusalẹmu ń ṣe hàn án, kí o sì sọ fún un pé, OLUWA Ọlọrun sọ nípa Jerusalẹmu pé: “Ilẹ̀ Kenaani ni a bí ọ sí; ibẹ̀ ni orísun rẹ. Ará Amori ni baba rẹ ará Hiti sì ni ìyá rẹ. Bí wọn ṣe bí ọ nìyí: nígbà tí wọ́n bí ọ, wọn kò dá ìwọ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi omi wẹ̀ ọ́. Wọn kò fi iyọ̀ pa ọ́ lára, wọn kò sì fi aṣọ wé ọ. Ẹnikẹ́ni kò wò ọ́ lójú, kí ó ṣàánú rẹ, kí ó ṣe ọ̀kan kan ninu àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì fún ọ. Ṣugbọn wọ́n gbé ọ sọ sinu pápá, nítorí pé wọ́n kórìíra rẹ ní ọjọ́ tí wọ́n bí ọ. “Bí mo tí ń rékọjá lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ, mo rí ọ tí ò ń ta ẹsẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀. Bí o tí ń yí ninu ẹ̀jẹ̀, mo bá sọ fún ọ pé kí o yè, kí o sì dàgbà bí irúgbìn oko. Ni o bá dàgbà, o ga, o sì di wundia, ọyàn rẹ yọ, irun rẹ sì hù, sibẹ o wà ní ìhòòhò. “Ìgbà tí mo tún kọjá lọ́dọ̀ rẹ, tí mo tún wò ọ́, o ti dàgbà o tó gbé. Mo bá da aṣọ mi bò ọ́, mo fi bo ìhòòhò rẹ. Mo ṣe ìlérí fún ọ, mo bá ọ dá majẹmu, o sì di tèmi. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “Lẹ́yìn náà, mo mú omi, mo wẹ̀ ọ́; mo fọ ẹ̀jẹ̀ kúrò lára rẹ, mo sì fi òróró pa ọ́ lára. Mo wá wọ̀ ọ́ ní aṣọ tí wọ́n ṣe ọnà sí lára, mo wọ̀ ọ́ ní bàtà aláwọ. Mo wọ̀ ọ́ ní aṣọ funfun, mo sì dá ẹ̀wù siliki fún ọ. Mo ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́, mo fi ẹ̀gbà sí ọ lọ́wọ́; mo sì fi ìlẹ̀kẹ̀ sí ọ lọ́rùn. Mo fi òrùka sí ọ nímú, mo fi yẹtí sí ọ létí, mo sì fi adé tí ó lẹ́wà dé ọ lórí. Bẹ́ẹ̀ ni mo fi wúrà ati fadaka ṣe ọ̀ṣọ́ sí ọ lára. Aṣọ funfun ati siliki tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára ni mo dá fún ọ. Ò ń jẹ burẹdi tí ó dùn, tí wọ́n fi ìyẹ̀fun tí ó kúnná ṣe, ò ń lá oyin ati òróró; o dàgbà, o sì di arẹwà, o dàbí Ọbabinrin. Òkìkí ẹwà rẹ wá kàn ká gbogbo orílẹ̀-èdè; o dára nítorí pé èmi ni mo fún ọ ní ẹwà. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “Ṣugbọn o gbójú lé ẹwà rẹ; o di alágbèrè ẹ̀sìn nítorí òkìkí rẹ, o sì ń bá gbogbo àwọn eniyan tí wọn ń kọjá ṣe àgbèrè. O mú ninu àwọn aṣọ rẹ, o fi ṣe ojúbọ aláràbarà, o sì ń ṣe àgbèrè ẹ̀sìn níbẹ̀. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣẹlẹ̀ mọ́. O mú ninu àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wúrà ati ti fadaka rẹ, tí mo fún ọ, o fi wọ́n ṣe ère ọkunrin, o sì ń bá wọn ṣe àgbèrè. O mú aṣọ rẹ tí a ṣe ọnà sí lára, o dà á bò wọ́n. O gbé òróró ati turari mi kalẹ̀ níwájú wọn. Bẹ́ẹ̀ náà ni oúnjẹ tí mo fún ọ. Mo fún ọ ní ìyẹ̀fun tí ó kúnná, ati òróró, ati oyin pé kí o máa jẹ, ṣugbọn o fi rú ẹbọ olóòórùn dídùn sí wọn. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “O mú àwọn ọmọ rẹ ọkunrin ati àwọn ọmọ rẹ obinrin tí o bí fún mi, o fi wọ́n rú ẹbọ ohun jíjẹ fún àwọn oriṣa. Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ kékeré ni o pe ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè ẹ̀sìn rẹ, tí o fi ọ̀bẹ dú àwọn ọmọ mi, o fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí àwọn oriṣa? Nígbà tí ò ń ṣe àgbèrè ati gbogbo nǹkan ìríra rẹ, o kò ranti ìgbà èwe rẹ, nígbà tí o wà ní ìhòòhò goloto, tí ò ń ta ẹsẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀!” OLUWA Ọlọrun ní, “Lẹ́yìn gbogbo iṣẹ́ ibi wọnyi, o gbé! O gbé! O mọ ilé gíga fún ara rẹ ní gbogbo gbàgede, o tẹ́ ìtẹ́ gíga fún ara rẹ ní ìta gbangba. O mọ ìtẹ́ gíga ní òpin gbogbo òpópó. O sì ń ba ẹwà rẹ jẹ́ níbẹ̀, ò ń ta ara rẹ fún gbogbo ọkunrin tí wọn ń kọjá, o sì sọ àgbèrè rẹ di pupọ. O tún ṣe àgbèrè ẹ̀sìn pẹlu àwọn ará Ijipti, àwọn aládùúgbò rẹ, oníṣekúṣe. Ò ń mú kí ìwà àgbèrè rẹ pọ̀ sí i láti mú mi bínú. “Ọwọ́ mi wá tẹ̀ ọ́, mo mú ọ kúrò ninu ẹ̀tọ́ rẹ. Mo jẹ́ kí àwọn ọ̀tá rẹ fi ìwọ̀ra gba ohun ìní rẹ, àwọn ará Filistini tí ìwà burúkú rẹ ń tì lójú. “O bá àwọn ará Asiria ṣe àgbèrè ẹ̀sìn pẹlu, nítorí pé o kò ní ìtẹ́lọ́rùn sibẹ, lẹ́yìn gbogbo àgbèrè tí o ṣe pẹlu wọn, o kò ní ìtẹ́lọ́rùn. O tún ṣe àgbèrè lọpọlọpọ pẹlu àwọn oníṣòwò ará ilẹ̀ Kalidea, sibẹsibẹ, kò tẹ́ ọ lọ́rùn.” OLUWA Ọlọrun ní ọkàn rẹ ti kún fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ jù! Ó ń wò ọ́ bí o tí ń ṣe gbogbo nǹkan wọnyi bí alágbèrè tí kò nítìjú! O mọ ilé oriṣa sí òpin gbogbo òpópó, o sì ń kọ́ ibi ìrúbọ sí gbogbo gbàgede. Sibẹ o kò ṣe bí àwọn alágbèrè, nítorí pé o kò gba owó. Ìwọ iyawo onípanṣágà tí ò ń kó àwọn ọkunrin ọlọkunrin wọlé dípò ọkọ rẹ. Ọkunrin níí máa ń fún àwọn aṣẹ́wó ní ẹ̀bùn, ṣugbọn ní tìrẹ, ìwọ ni ò ń fún àwọn olólùfẹ́ rẹ lẹ́bùn. O fi ń tù wọ́n lójú, kí wọ́n lè máa wá bá ọ ṣe àgbèrè láti ibi gbogbo. Àgbèrè tìrẹ yàtọ̀ sí ti àwọn aṣẹ́wó yòókù, kò sí ẹni tí ń wá ọ láti bá ọ ṣe àgbèrè; ìwọ ni ò ń fún ọkunrin ní ẹ̀bùn dípò kí wọ́n fún ọ! Èyí ni àgbèrè tìrẹ fi yàtọ̀ sí ti àwọn ẹlòmíràn. Nítorí náà, ìwọ aṣẹ́wó yìí, gbọ́ ohun tí OLUWA wí. OLUWA Ọlọrun ní, “Ìwà ìtìjú rẹ ti hàn sí gbangba, o bọ́ra sí ìhòòhò níta, nígbà tí ò ń bá àwọn olólùfẹ́ rẹ ṣe àgbèrè, tí ò ń bọ àwọn oriṣa rẹ, o sì pa àwọn ọmọ rẹ, o fi wọ́n rúbọ sí àwọn oriṣa. Wò ó! N óo kó gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ, tí inú rẹ dùn sí jọ, ati àwọn tí o fẹ́ràn ati àwọn tí o kórìíra, ni n óo kó wá láti dojú kọ ọ́ ní gbogbo ọ̀nà. N óo tú ọ sí ìhòòhò lójú wọn, kí wọ́n lè rí ìhòòhò rẹ. N óo ṣe ìdájọ́ fún ọ bí wọn tí ń ṣe ìdájọ́ fún àwọn obinrin tí wọ́n kọ ọkọ sílẹ̀, tabi àwọn tí wọ́n paniyan. N óo fi ìtara ati ibinu gbẹ̀san ìpànìyàn lára rẹ. N óo fi ọ́ lé àwọn olólùfẹ́ rẹ lọ́wọ́, wọn óo wó ilé oriṣa ati ibi ìrúbọ rẹ palẹ̀. Wọn óo tú aṣọ rẹ, wọn óo gba àwọn ohun ọ̀ṣọ́ rẹ, wọn yóo sì fi ọ́ sílẹ̀ ní ìhòòhò. “Wọn óo kó àwọn ọmọ ogun wá bá ọ, wọn óo sọ ọ́ lókùúta, wọn óo sì fi idà wọn gé ọ sí wẹ́wẹ́. Wọn óo dáná sun àwọn ilé rẹ, wọn óo sì ṣe ìdájọ́ fún ọ lójú àwọn obinrin pupọ. N kò ní jẹ́ kí o ṣe àgbèrè mọ́, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní jẹ́ kí o fún àwọn olólùfẹ́ rẹ ní ẹ̀bùn mọ́. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lára rẹ, n kò sì ní jowú nítorí rẹ mọ́. Ara mi yóo rọlẹ̀, inú kò sì ní bí mi mọ́. Nítorí pé o kò ranti ìgbà èwe rẹ, ṣugbọn o mú mi bínú nítorí nǹkan wọnyi. Nítorí náà n óo da èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ lé ọ lórí. Ṣé o kò tún ti fi ìwà ainitiju kún ìwà ìríra rẹ?” OLUWA Ọlọrun ni ó sọ bẹ́ẹ̀. OLUWA ní: “Gbogbo eniyan ni yóo máa pa òwe yìí mọ́ ìwọ Jerusalẹmu pé: ‘Òwú ìyá gbọ̀n ni ọmọ óo ran, bí ìyá bá ti rí ni ọmọ rẹ̀ obinrin yóo rí.’ Ọmọ bíbí inú ìyá rẹ ni ọ́, tí kò bìkítà fún ọkọ ati àwọn ọmọ rẹ̀. Ìwà kan náà ni ó wà lọ́wọ́ ìwọ ati àwọn arabinrin rẹ, àwọn náà kò ka ọkọ ati àwọn ọmọ wọn sí. Ará Hiti ni ìyá rẹ, ará Amori sì ni baba rẹ. “Samaria ni ẹ̀gbọ́n rẹ, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ń gbé ìhà àríwá. Sodomu ni àbúrò rẹ, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ń gbé ìhà gúsù. Títẹ̀lé ìṣe wọn nìkan kò tẹ́ ọ lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ ni ṣíṣe ohun ìríra bíi tiwọn kò tó ọ. Láìpẹ́ ọjọ́, ìwà tìrẹ gan-an yóo burú ju tiwọn lọ. “Èmi OLUWA Ọlọrun fi ara mi búra pé, Sodomu arabinrin rẹ ati àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin kò tíì ṣe tó ohun tí ìwọ ati àwọn ọmọbinrin rẹ ṣe. Ohun tí Sodomu arabinrin rẹ ṣe tí kò dára ni pé: Òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin ní ìgbéraga. Wọ́n ní oúnjẹ lọpọlọpọ, ara sì rọ̀ wọ́n, ṣugbọn wọn kò ran talaka ati aláìní lọ́wọ́. Wọ́n gbéraga, wọ́n sì ṣe nǹkan ìríra níwájú mi. Nítorí náà, nígbà tí mo rí ohun tí wọn ń ṣe, mo pa wọ́n run. “Ẹ̀ṣẹ̀ tí Samaria dá kò tó ìdajì èyí tí ìwọ dá, ohun ìríra tí o ṣe sì jù tiwọn lọ. O ti mú kí arabinrin rẹ dàbí olódodo lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ, nítorí pé nǹkan ìríra tí o ṣe pọ̀ pupọ ju tirẹ̀ lọ. Ó yẹ kí ojú ti ìwọ pàápàá, nítorí o ti jẹ́ kí ìdájọ́ gbe àwọn arabinrin rẹ, nítorí nǹkan ìríra tí o ṣe ju tiwọn lọ. Ọ̀nà wọn tọ́ ju tìrẹ lọ, nítorí náà, ó yẹ kí ojú tì ọ́, nítorí o ti mú kí àwọn arabinrin rẹ dàbí olódodo lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ.” OLUWA sọ níti Jerusalẹmu pé, “N óo dá ire wọn pada: ire Sodomu ati ti àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin ati ire Samaria ati ti àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin. N óo dá ire tìrẹ náà pada pẹlu tiwọn. Kí ojú lè tì ọ́ fún gbogbo ohun tí o ṣe tí o fi dá wọn lọ́kàn le. Ní ti àwọn arabinrin rẹ: Sodomu ati àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin yóo pada sí ibùgbé wọn, Samaria ati àwọn ọmọ rẹ obinrin yóo pada sí ibùgbé wọn, ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin náà yóo pada sí ibùgbé yín. Ṣebí yẹ̀yẹ́ ni ò ń fi Sodomu arabinrin rẹ ṣe ní àkókò tí ò ń gbéraga, kí ó tó di pé àṣírí ìwà burúkú rẹ wá tú? Nisinsinyii ìwọ náà ti dàbí rẹ̀; o ti di ẹni yẹ̀yẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọbinrin Edomu ati àwọn tí ó wà ní agbègbè wọn, ati lọ́wọ́ àwọn ọmọbinrin Filistini, ati àwọn tí wọ́n yí ọ ká, tí wọn ń kẹ́gàn rẹ. O óo jìyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ati àwọn nǹkan ìríra tí o ṣe. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” Láìṣe àní, àní, OLUWA Ọlọrun ní, “N óo ṣe sí ọ, bí ìwà rẹ. O kò ka ìbúra mi sí, o sì ti yẹ majẹmu mi. Sibẹsibẹ, n óo ranti majẹmu tí mo bá ọ dá ní ìgbà èwe rẹ. N óo sì bá ọ dá majẹmu tí kò ní yẹ̀ títí lae. O óo wá ranti gbogbo ìwà rẹ, ojú yóo sì tì ọ́ nígbà tí mo bá mú ẹ̀gbọ́n rẹ obinrin ati àbúrò rẹ obinrin, tí mo sì fà wọ́n lé ọ lọ́wọ́ bí ọmọ; ṣugbọn tí kò ní jẹ́ pé torí majẹmu tí mo bá ọ dá ni. N óo fìdí majẹmu tí mo bá ọ dá múlẹ̀. O óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA. Kí o lè ranti, kí ìdààmú sì bá ọ, kí ìtìjú má jẹ́ kí o lè lanu sọ̀rọ̀ mọ́; nígbà tí mo bá dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, pa àlọ́ kan kí o sì fi òwe bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀. Wí fún wọn pé, OLUWA Ọlọrun ní idì ńlá kan wá sí Lẹbanoni, apá rẹ̀ tóbi, ìrù rẹ̀ sì gùn, ó sì ní ìyẹ́ aláràbarà. Ó bá bà lé ṣóńṣó orí igi kedari kan, ó ṣẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ lórí, ó gbé e lọ sí ilẹ̀ àwọn oníṣòwò; ó fi sí ìlú àwọn tí ń ta ọjà. Lẹ́yìn náà, ó mú ninu èso ilẹ̀ náà, ó gbìn ín sí ilẹ̀ kan tí ó lọ́ràá, ní ẹ̀bá odò. Ó gbìn ín bí wọn tíí gbin igi wilo. Igi yìí hù, ó dàbí àjàrà tí kò ga, ṣugbọn tí ó tàn kálẹ̀. Ẹ̀ka rẹ̀ nà sọ́dọ̀ idì yìí lókè, ṣugbọn gbòǹgbò rẹ̀ kò kúrò níbi tí ó wà. Ó di àjàrà, ó yọ ẹ̀ka, ó sì rúwé. “Idì ńlá mìíràn tún wà, apá rẹ̀ tóbi, ìyẹ́ rẹ̀ sì pọ̀ lọpọlọpọ. Àjàrà yìí bá kọ orí gbòǹgbò ati ẹ̀ka rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ idì ńlá yìí, kí Idì náà lè máa bomi rin ín. Idì yìí bá hú u níbi tí wọ́n gbìn ín sí, ó lọ gbìn ín sí ilẹ̀ kan tí ó lọ́ràá lẹ́bàá odò, kí ó lè yọ ẹ̀ka, kí ó so èso, kí ó sì di àjàrà ńlá tí ó níyì. “Sọ fún wọn pé, èmi OLUWA Ọlọrun ní kí o bèèrè lọ́wọ́ wọn pé, ‘Ṣé àjàrà yìí yóo ṣe dáradára? Ṣé idì ti àkọ́kọ́ kò ní fa gbòǹgbò rẹ̀ tu, kí ó gé ẹ̀ka rẹ̀, kí àwọn ewé rẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ sì rọ?’ Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ nílò alágbára tabi ọ̀pọ̀ eniyan, láti fà á tu tigbòǹgbò tigbòǹgbò. Nígbà tí wọ́n bá tún un gbìn ǹjẹ́ yóo yè? Ṣé kò ní gbẹ patapata nígbà tí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn bá fẹ́ lù ú? Yóo gbẹ níbi tí wọ́n gbìn ín sí.” Lẹ́yìn náà, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Bi àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọnyi pé, ṣé wọn kò mọ ìtumọ̀ òwe wọnyi ni? Sọ pé ọba Babiloni wá sí Jerusalẹmu, ó sì kó ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ ní Babiloni. Ó mú ọ̀kan ninu àwọn ìdílé ọba, ó bá a dá majẹmu, ó sì mú kí ó búra. Ó ti kọ́ kó gbogbo àwọn eniyan pataki pataki ilẹ̀ náà lọ, kí ilẹ̀ náà lè di ìrẹ̀sílẹ̀, kí wọ́n má sì lè gbérí mọ́, ṣugbọn kí ilẹ̀ náà lè máa ní ìtẹ̀síwájú, níwọ̀n ìgbà tí ó bá pa majẹmu ọba Babiloni mọ́. Ṣugbọn ọba Juda ṣọ̀tẹ̀ sí ti Babiloni, ó rán ikọ̀ lọ sí Ijipti pé kí wọ́n fún òun ní ẹṣin ati ọpọlọpọ ọmọ ogun. Ǹjẹ́ yóo ní àṣeyọrí? Ṣé ẹni tí ń ṣé irú èyí lè bọ́? Ṣé ó lè yẹ majẹmu náà kí ó sì bọ́ ninu rẹ̀? “Èmi OLUWA fi ara mi búra pé, ní ilẹ̀ Babiloni, ní ilẹ̀ ọba tí ó fi í sórí oyè ọba tí kò náání, tí ó sì da majẹmu rẹ̀, níbẹ̀ ni yóo kú sí. Farao, pẹlu ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ati ọpọlọpọ eniyan rẹ̀, kò ní lè ràn án lọ́wọ́ nígbà ogun; nígbà tí ogun bá dótì í, tí wọ́n sì mọ òkítì sí ara odi rẹ̀ láti pa ọpọlọpọ eniyan. Kò ní sá àsálà, nítorí pé kò náání ìbúra ó sì da majẹmu, ati pé ó ti tọwọ́ bọ ìwé, sibẹsibẹ, ó tún ṣe gbogbo nǹkan tí ó ṣe.” Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “Mo fi ara mi búra, n óo gbẹ̀san ìbúra mi tí kò náání lára rẹ̀, ati majẹmu mi tí ó dà. N óo da àwọ̀n mi bò ó mọ́lẹ̀, pańpẹ́ mi yóo mú un, n óo sì mú un lọ sí Babiloni. Níbẹ̀ ni n óo ti ṣe ìdájọ́ rẹ̀ nítorí ìwà ọ̀tẹ̀ tí ó hù sí mi. Idà ni wọn óo fi pa àwọn tí wọ́n bá sá lára àwọn ọmọ ogun rẹ̀, a óo sì fọ́n àwọn tí wọ́n bá kù ká sí gbogbo ayé, ẹ óo wá mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo sọ̀rọ̀.” OLUWA Ọlọrun ní: “Èmi fúnra mi ni n óo mú ọ̀kan ninu ẹ̀ka kan ní ṣóńṣó igi Kedari gíga, n óo ṣẹ́ ẹ̀ka kan láti orí rẹ̀, n óo gbìn ín sí orí òkè gíga fíofío. Lórí òkè gíga Israẹli ni n óo gbìn ín sí, kí ó lè yọ ẹ̀ka, kí ó so, kí ó sì di igi Kedari ńlá. Oríṣìíríṣìí ẹranko ìgbẹ́ ni yóo máa gbé abẹ́ rẹ̀. Oríṣìíríṣìí ẹyẹ yóo pa ìtẹ́ sí abẹ́ òjìji ẹ̀ka rẹ̀. Gbogbo igi inú igbó yóo mọ̀ pé èmi, OLUWA, ni èmi í sọ igi ńlá di kékeré, mà sì máa sọ igi kékeré di ńlá. Mà máa sọ igi tútù di gbígbẹ, má sì máa mú kí igi gbígbẹ pada rúwé. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n óo sì ṣe.” OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó bi mí pé: “Kí ni ẹ rí tí ẹ fi ń pa irú òwe yìí nípa ilẹ̀ Israẹli, tí ẹ̀ ń sọ pé, ‘Àwọn baba ni wọ́n jẹ èso àjàrà tí ó kan, ni eyín fi kan àwọn ọmọ?’ “Mo fi ara mi búra pé, ẹ kò ní pa òwe yìí mọ́ ní ilẹ̀ Israẹli. Èmi ni mo ni ẹ̀mí gbogbo eniyan, tèmi ni ẹ̀mí baba ati ẹ̀mí ọmọ; ẹni yòówù tó bá dẹ́ṣẹ̀ ni yóo kú. “Bí ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ olódodo, tí ó ń ṣe ohun tí ó tọ́, tí ó sì bá òfin mu; bí kò bá bá wọn jẹ ẹbọ lórí àwọn òkè, tabi kí ó bọ àwọn oriṣa ilé Israẹli; tí kò bá bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀, tabi kí ó bá obinrin lòpọ̀ ní àkókò tí ó ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀ lọ́wọ́; tí kò ni ẹnikẹ́ni lára, ṣugbọn tí ó dá ohun tí onígbèsè fi ṣe ìdúró pada fún un; tí kò fi ipá jalè, tí ó ń fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ, tí ó sì ń da aṣọ bo ẹni tí ó wà ní ìhòòhò, tí kò gba owó èlé lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, tí ó yàgò fún ẹ̀ṣẹ̀, tí ó ń dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ láàrin ẹni meji, tí ó ń rìn ninu ìlànà mi, tí ó sì ń fi tọkàntọkàn pa òfin mi mọ́, olódodo ni irú ẹni bẹ́ẹ̀, yóo sì yè. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “Bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá bí ọmọ, tí ọmọ yìí ń fi ipá jalè, tí ń pa eniyan, tí kò ṣe ọ̀kankan ninu gbogbo ohun tí a kà sílẹ̀ pé baba ń ṣe, ṣugbọn tí ó ń jẹ ẹbọ lórí àwọn òkè, tí ó ń bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀; tí ń ni talaka ati aláìní lára, tí ń fi ipá jalè, tí kì í dá ohun tí onígbèsè rẹ̀ bá fi ṣe ìdúró pada fún un, tí ń bọ oriṣa, tí ń ṣe ohun ìríra, tí ń gba owó èlé; ǹjẹ́ irú eniyan bẹ́ẹ̀ lè yè? Kò lè yè rárá. Nítorí pé ó ti ṣe àwọn ohun ìríra wọnyi, yóo kú ni dájúdájú; lórí ara rẹ̀ sì ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà. “Ṣugbọn bí eniyan burúkú yìí bá bí ọmọ, tí ọmọ yìí rí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí baba rẹ̀ ń dá, tí ẹ̀rù bà á, tí kò sì ṣe bíi baba rẹ̀, tí kì í jẹ ẹbọ lórí àwọn òkè, tí kò bọ àwọn oriṣa ilé Israẹli, tí kò bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀, tí kò ṣẹ ẹnikẹ́ni; tí Kì í gba ohun ìdúró lọ́wọ́ onígbèsè, tí kì í fi ipá jalè, ṣugbọn tí ń fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ, tí sì ń da aṣọ bo ẹni tí ó wà ní ìhòòhò, tí ó yàgò fún ẹ̀ṣẹ̀, tí kì í gba owó èlé, tí ń pa òfin mi mọ́, tí sì ń rìn ninu ìlànà mi, kò ní kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀, dájúdájú yóo yè. Baba rẹ̀ yóo kú ní tirẹ̀, nítorí pé ó ń fi ipá gbowó, ó ń ja arakunrin rẹ̀ lólè, ó sì ń ṣe ohun tí kò dára sí àwọn eniyan rẹ̀; nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀ ni yóo ṣe kú. “Sibẹsibẹ ẹ̀ ń sọ pé, ‘Kí ló dé tí ọmọ kò fi ní jìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀?’ Níwọ̀n ìgbà tí ọmọ bá ti ṣe ohun tí ó bá òfin mu, tí ó sì ti mú gbogbo ìlànà mi ṣẹ; dájúdájú yóo yè ni. Ẹni tí ó bá ṣẹ̀ ni yóo kú: ọmọ kò ní jìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀; baba kò sì ní jìyà ẹ̀ṣẹ̀ ọmọ rẹ̀. Olódodo yóo jèrè òdodo rẹ̀; bẹ́ẹ̀ sì ni eniyan burúkú yóo jèrè ìwà burúkú rẹ̀. “Ṣugbọn bí eniyan burúkú bá yipada kúrò ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ń dá, tí ó ń pa òfin mi mọ́, tí ó ń ṣe ohun tí ó tọ́, tí ó sì bá òfin mu, dájúdájú yóo yè ni, kò ní kú. A kò ní ranti gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, yóo yè nítorí òdodo rẹ̀.” OLUWA ní: “A máa ṣe pé mo ní inú dídùn sí ikú ẹlẹ́ṣẹ̀ ni? Ṣebí ohun tí mo fẹ́ ni pé kí ó yipada kúrò lọ́nà burúkú rẹ̀, kí ó sì yè. “Ṣugbọn bí olódodo bá yipada kúrò ninu ìwà òdodo rẹ̀, tí ó bá bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́ṣẹ̀, tí ó ń ṣe àwọn ohun ìríra tí àwọn eniyan burúkú ń ṣe; ṣé irú ẹni bẹ́ẹ̀ leè yè? Rárá! A kò ní ranti gbogbo òdodo rẹ̀ tí ó ti ṣe mọ́, yóo kú nítorí ìwà ọ̀tẹ̀ ati ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. “Sibẹsibẹ ẹ̀ ń sọ pé, ‘Ọ̀nà OLUWA kò tọ́.’ Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli: ọ̀nà tèmi ni kò tọ́ ni, àbí ọ̀nà tiyín? Bí olódodo bá yipada kúrò ninu ìwà òdodo rẹ̀, tí ó bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́ṣẹ̀, yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá. Bí eniyan burúkú bá sì yipada kúrò ninu ìwà ibi rẹ̀, tí ó sì ń ṣe rere, yóo gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là. Nítorí pé ó ronú, ó sì yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ń dá, dájúdájú yóo yè, kò ní kú. Sibẹsibẹ àwọn ọmọ Israẹli ń wí pé, ‘Ọ̀nà OLUWA kò tọ́.’ Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ṣé ọ̀nà mi ni kò tọ́, àbí tiyín? “Nítorí náà, n óo da yín lẹ́jọ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli. Ìwà olukuluku ni n óo fi dá a lẹ́jọ́. Ẹ ronupiwada, kí ẹ sì yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ̀ṣẹ̀ má baà pa yín run. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Ẹ kọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín tí ẹ̀ ń dá sí mi sílẹ̀. Ẹ wá ọkàn tuntun ati ẹ̀mí tuntun fún ara yín. Kí ló dé tí ẹ fi fẹ́ kú, ẹ̀yin ọmọ ilé Israẹli? N kò ní inú dídùn sí ikú ẹnikẹ́ni, nítorí náà, ẹ yipada kí ẹ lè yè. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA ní kí n sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn nítorí àwọn olórí Israẹli, kí n sọ pé: Abo kinniun pataki ni ìyá rẹ láàrin àwọn kinniun! Ó dùbúlẹ̀ láàrin àwọn ọ̀dọ́ kinniun, ó ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀. Ó tọ́ ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ dàgbà; ó di ọ̀dọ́ kinniun. Ó kọ́ ọ bí wọ́n tí ń ṣe ọdẹ, ó sì ń pa eniyan jẹ. Àwọn eniyan ayé gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n tàn án sinu kòtò wọn. Wọ́n fi ìwọ̀ kọ́ ọ nímú, wọ́n sì fà á lọ sí ilẹ̀ Ijipti. Nígbà tí abo kinniun náà rí i pé ọwọ́ tẹ ọmọ òun, ati pé igbẹkẹle òun ti dòfo, ó mú òmíràn ninu àwọn ọmọ rẹ̀, ó tọ́ ọ di ọ̀dọ́ kinniun. Ó ń yan kiri láàrin àwọn kinniun; nítorí ó ti di ọ̀dọ́ kinniun tí ó lágbára, ó kọ́ bí wọn tí ń ṣe ọdẹ, ó sì ń pa eniyan jẹ. Ó wó ilé ìṣọ́ wọn lulẹ̀; ó sọ ìlú wọn di ahoro. Ẹ̀rù ba gbogbo Ilẹ̀ náà, ati gbogbo àwọn tí ń gbé ibẹ̀, nígbà tí wọ́n gbọ́ bíbú rẹ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè bá dójú lé e, wọ́n dẹ tàkúté fún un ní gbogbo ọ̀nà, wọ́n da àwọ̀n wọn bò ó, wọ́n sì mú un ninu kòtò tí wọn gbẹ́ fún un. Wọ́n sọ ìwọ̀ sí i nímú, wọ́n gbé e jù sinu àhámọ́, wọ́n sì fà á lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babiloni. Wọ́n fi sí àtìmọ́lé, kí wọ́n má baà gbọ́ ohùn rẹ̀ mọ́ lórí àwọn òkè Israẹli. Ìyá rẹ dàbí àjàrà inú ọgbà tí a gbìn sí ẹ̀gbẹ́ odò; ó rúwé, ó yọ ẹ̀ka, nítorí ó rí omi lọpọlọpọ. Ẹ̀ka rẹ̀ tí ó lágbára ni a fi gbẹ́ ọ̀pá àṣẹ fún àwọn olórí. Ó dàgbà, ó ga fíofío, láàrin àwọn igi igbó. Ó rí i bí ó ti ga, tí ẹ̀ka rẹ̀ sì pọ̀. Ṣugbọn a fa àjàrà náà tu pẹlu ibinu, a sì jù ú sílẹ̀. Afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn mú kí ó gbẹ, gbogbo èso rẹ̀ sì rẹ̀ dànù. Igi rẹ̀ tí ó lágbára gbẹ, iná sì jó o. Nisinsinyii, a ti tún un gbìn sinu aṣálẹ̀, ninu ilẹ̀ gbígbẹ níbi tí kò sí omi. Iná ṣẹ́ lára igi rẹ̀, ó sì jó gbogbo ẹ̀ka ati èso rẹ̀. Kò sì ní igi tí ó lágbára mọ́, tí a lè fi gbẹ́ ọ̀pá àṣẹ fún ọba. Dájúdájú ọ̀rọ̀ arò ni ọ̀rọ̀ yìí, ó sì ti di orin arò. Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù karun-un, ọdún keje tí a ti wà ní ìgbèkùn, àwọn àgbààgbà Israẹli kan wá láti wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ OLUWA, wọ́n sì jókòó níwájú mi. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan sọ fún àwọn àgbààgbà Israẹli pé, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Ṣé ẹ wá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ mi ni? Mo fi ara mi búra pé, n kò ní da yín lóhùn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ “Ṣé o óo ṣe ìdájọ́ wọn? Ìwọ ọmọ eniyan, ṣé o óo ṣe ìdájọ́ wọn? Jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn nǹkan ìríra tí àwọn baba wọn ṣe. Kí o sì sọ fún wọn pé èmi OLUWA ní, ní ọjọ́ tí mo yan Israẹli, mo búra fún àwọn ọmọ Jakọbu, mo fi ara mi hàn fún wọn ní ilẹ̀ Ijipti, mo sì búra fún wọn pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn. Ní ọjọ́ náà, mo búra fún wọn pé n óo yọ wọ́n kúrò ni ilẹ̀ Ijipti, n óo sì mú wọn dé ilẹ̀ tí mo ti wá sílẹ̀ fún wọn, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin, ilẹ̀ tí ó lógo jùlọ láàrin gbogbo ilẹ̀ ayé. Mo wí fún wọn pé kí olukuluku kọ àwọn nǹkan ẹ̀gbin tí ó gbójú lé sílẹ̀, kí ẹ má sì fi àwọn oriṣa ilẹ̀ Ijipti, ba ara yín jẹ́; nítorí pé èmi ni OLUWA Ọlọrun yín. Ṣugbọn wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí mi, wọn kò sì gbọ́ tèmi, ẹnìkankan ninu wọn kò mójú kúrò lára àwọn ère tí wọ́n ń bọ tẹ́lẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kọ àwọn oriṣa Ijipti sílẹ̀. Mo kọ́ rò ó pé kí n bínú sí wọn, kí n sì tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lára wọn ní ilẹ̀ Ijipti. Ṣugbọn mo tún ro ti orúkọ mi, nítorí n kò fẹ́ kí wọ́n ba orúkọ mi jẹ́ láàrin àwọn eniyan tí wọn ń gbé, lójú àwọn tí mo ti fi ara mi hàn wọ́n ní ilẹ̀ Ijipti, nígbà tí mo kó wọn jáde kúrò níbẹ̀. “Nítorí náà, mo kó wọn kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, wá sinu aṣálẹ̀. Mo fún wọn ní òfin mi, mo sì fi ìlànà mi hàn wọ́n, èyí tí ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé yóo yè. Lẹ́yìn náà, mo fún wọn ní ọjọ́ ìsinmi, kí ó máa jẹ́ àmì láàrin èmi pẹlu wọn, kí wọ́n lè mọ̀ pé èmi OLUWA yà wọ́n sí mímọ́. Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli dìtẹ̀ sí mi ninu aṣálẹ̀, wọn kò pa òfin mi mọ́; wọ́n sì kọ ìlànà mi sílẹ̀, èyí tí ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé yóo yè. Wọ́n ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́ patapata. Lẹ́yìn náà mo kọ́ gbèrò ati fi ibinu pa wọ́n run patapata ninu aṣálẹ̀. Ṣugbọn mo tún ro ti orúkọ mi, nítorí n kò fẹ́ kí wọ́n ba orúkọ mi jẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí mo ti kó wọn jáde. Nítorí náà, mo búra fún wọn ninu aṣálẹ̀ pé n kò ní mú wọn dé ilẹ̀ tí mo ti ṣèlérí pé n óo fún wọn, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin, ilẹ̀ tí ó lógo jù ní gbogbo ilẹ̀ ayé. Nítorí pé wọ́n kọ ìlànà mi sílẹ̀, wọn kò tẹ̀lé òfin mi, wọ́n sì ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́, nítorí pé ọkàn wọn kò kúrò lọ́dọ̀ àwọn oriṣa wọn. “Sibẹsibẹ mo fojú àánú wò wọ́n, n kò pa wọ́n run sinu aṣálẹ̀. Mo sọ fún àwọn ọmọ wọn ninu aṣálẹ̀ pé kí wọ́n má tọ ọ̀nà tí àwọn baba wọn rìn, kí wọ́n má ṣe tẹ̀lé òfin wọn, tabi kí wọ́n bọ oriṣa wọn. Mo ní èmi OLUWA ni Ọlọrun yín. Ẹ máa rìn ní ọ̀nà mi, kí ẹ sì máa pa òfin mi mọ́. Ẹ máa pa àwọn ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, kí wọ́n lè jẹ́ àmì láàrin èmi pẹlu yín, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi OLUWA ni Ọlọrun yín. “Ṣugbọn, àwọn ọmọ náà ṣọ̀tẹ̀ sí mi: wọn kò tẹ̀lé ìlànà mi, wọn kò sì fi tọkàntọkàn pa òfin mi mọ́, èyí tí ó jẹ́ pé bí eniyan bá tẹ̀lé ni yóo yè, wọ́n sì tún ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́. Lẹ́yìn náà mo kọ́ gbèrò ati fi ibinu pa wọ́n run patapata, kí n tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lórí wọn ninu aṣálẹ̀. Ṣugbọn mo rowọ́, mo sì ro ti orúkọ mi, tí n kò fẹ́ kí wọ́n bàjẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí mo ti kó wọn jáde. Nítorí náà, mo ṣe ìlérí fún wọn ninu aṣálẹ̀ pé n óo fọ́n wọn káàkiri láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, nítorí pé wọn kò pa òfin mi mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n kọ ìlànà mi sílẹ̀, wọ́n ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́, wọn kò sì mójú kúrò lára àwọn oriṣa tí àwọn baba wọn ń bọ. “Nítorí náà, mo fún wọn ní àṣẹ tí kò dára ati ìlànà tí kò lè gbà wọ́n là. Mo jẹ́ kí ẹbọ wọn sọ wọ́n di aláìmọ́, mọ jẹ́ kí wọ́n máa sun àkọ́bí wọn ninu iná, kí ìpayà lè bá wọn, kí wọ́n lè mọ̀ pé èmi ni OLUWA. “Nítorí náà, ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé èmi OLUWA Ọlọrun ní Ọ̀nà mìíràn tí àwọn baba yín tún fi bà mí lórúkọ jẹ́ ni pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí mi. Nígbà tí mo mú wọn dé ilẹ̀ tí mo búra pé n óo fún wọn, bí wọ́n bá ti rí òkè kan tí ó ga, tabi tí wọ́n rí igi kan tí ewé rẹ̀ pọ̀, wọn a bẹ̀rẹ̀ sí gbé ẹbọ wọn kalẹ̀ sibẹ. Wọn a rú ẹbọ ìríra, wọn a mú kí òórùn dídùn ẹbọ wọn bo gbogbo ibẹ̀, wọ́n a sì bẹ̀rẹ̀ sí ta ohun mímu sílẹ̀. Mo bi wọ́n léèrè pé irú ibi pẹpẹ ìrúbọ wo ni ẹ tilẹ̀ ń lọ ríì? Nítorí náà ni wọ́n ṣe ń pe ibẹ̀ ní Bama títí di òní. Nítorí náà, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé èmi OLUWA Ọlọrun ní ṣé ẹ óo máa ba ara yín jẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba yín, ẹ óo sì máa ṣìnà tẹ̀lé àwọn nǹkan ìríra wọn? Ẹ̀ ń rú àwọn ẹbọ yín, ẹ sì ń fi àwọn ọmọkunrin yín rú ẹbọ sísun, ẹ sì ti fi oriṣa bíbọ ba ara yín jẹ́ títí di òní. Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ṣé ẹ óo tún máa wá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ mi? Mo fi ara mi búra pé, ẹ kò ní rídìí ọ̀rọ̀ kankan lọ́dọ̀ mi. Èrò ọkàn yín kò ní ṣẹ: ẹ̀ ń gbèrò ati dàbí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ati àwọn ẹ̀yà tí ó wà ní agbègbè yín, kí ẹ máa bọ igi ati òkúta. “Mo fi ara mi búra, dájúdájú, tipátipá, pẹlu ibinu ati ọwọ́ líle ni n óo fi jọba lórí yín. N óo ko yín jáde láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, n óo ko yín jọ láti gbogbo ilẹ̀ tí mo ti fi tipátipá fọ́n yín ká sí, pẹlu ọwọ́ líle, ati ibinu. N óo ko yín lọ sinu aṣálẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, níbẹ̀ ni n óo ti dájọ́ yín lojukooju. Bí mo ṣe dájọ́ àwọn baba ńlá yín ní aṣálẹ̀ ilẹ̀ Ijipti ni n óo dájọ́ yín. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “N óo mú kí ẹ gba abẹ́ ọ̀pá mi kọjá, n óo sì mu yín wá sí abẹ́ ìdè majẹmu. N óo ṣa àwọn ọlọ̀tẹ̀ ati àwọn tí ń ṣe oríkunkun sí mi kúrò láàrin yín. N óo mú wọn kúrò ní ilẹ̀ tí wọ́n ti jẹ́ àlejò, ṣugbọn wọn kò ní dé ilẹ̀ Israẹli. Ẹ óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.” Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, OLUWA Ọlọrun ní, “Kí olukuluku yín lọ máa bọ oriṣa rẹ̀ láti ìsinsìnyìí lọ, bí ẹ kò bá fẹ́ gbọ́ tèmi, ṣugbọn ẹ kò ní fi ẹbọ ati oriṣa yín ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mọ́. Lórí òkè mímọ́ mi, lórí òkè gíga Israẹli, ni gbogbo ẹ̀yin ọmọ ilé Israẹli yóo ti máa sìn mí. Gbogbo yín pátá ní ilẹ̀ náà, ni ẹ óo máa sìn mí níbẹ̀. N óo yọ́nú si yín. N óo sì bèèrè ọrẹ àdájọ lọ́wọ́ yín ati ọrẹ àtinúwá tí ó dára jùlọ pẹlu ẹbọ mímọ́ yín. N óo yọ́nú si yín bí ìgbà tí mo bá gbọ́ òórùn ẹbọ dídùn, nígbà tí mo bá ń ko yín jáde kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, tí mò ń ko yín jọ kúrò láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè tí ẹ fọ́nká sí. Ẹwà mímọ́ mi yóo sì hàn lára yín lójú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá ko yín dé ilẹ̀ Israẹli, ilẹ̀ tí mo búra láti fún àwọn baba ńlá yín. Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà, ẹ óo ranti ìṣe yín, ati gbogbo ìwà èérí tí ẹ hù tí ẹ fi ba ara yín jẹ́. Ojú ara yín yóo sì tì yín nígbà tí ẹ bá ranti gbogbo nǹkan burúkú tí ẹ ti ṣe. Ẹ óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá ba yín wí nítorí orúkọ mi, tí kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwà burúkú yín tabi gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà burúkú yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA sọ fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú sí ìhà gúsù, fi iwaasu bá ìhà ibẹ̀ wí, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ilẹ̀ igbó Nẹgẹbu. Sọ fún igbó ibẹ̀ pé èmi OLUWA Ọlọrun ní n óo sọ iná sí i, yóo sì jó gbogbo àwọn igi inú rẹ̀, ati tútù ati gbígbẹ, iná náà kò ní kú. Yóo jó gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní gúsù títí dé àríwá. Gbogbo eniyan ni yóo rí i pé èmi OLUWA ni mo dá iná náà, kò sì ní ṣe é pa.” Mo bá dáhùn pé, “Áà! OLUWA Ọlọrun, wọ́n ń sọ nípa mi pé, ‘Ǹjẹ́ òun fúnrarẹ̀ kọ́ ni ó ń ro òwe yìí, tí ó sì ń pa á mọ́ wa?’ ” OLUWA bá mi sọ̀rọ̀; ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú sí Jerusalẹmu kí o sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí ibi mímọ́ Israẹli. Sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ Israẹli. Sọ fún ilẹ̀ náà pé OLUWA ní, ‘Wò ó, mo ti dojú kọ ọ́, n óo yọ idà mi ninu àkọ̀ rẹ̀, n óo sì pa àwọn eniyan inú rẹ: ati àwọn eniyan rere ati àwọn eniyan burúkú. N óo pa àwọn eniyan rere ati àwọn eniyan burúkú tí ó wà ninu rẹ run, nítorí náà, n óo yọ idà mi ninu àkọ̀ rẹ̀, n óo sì bẹ̀rẹ̀ sí pa gbogbo eniyan láti ìhà gúsù títí dé ìhà àríwá. Gbogbo eniyan yóo sì mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo fa idà mi yọ, n kò sì ní dá a pada sinu àkọ̀ mọ́.’ “Ìwọ ọmọ eniyan, máa mí ìmí ẹ̀dùn, bí ẹni tí ọkàn rẹ̀ ti dàrú, tí ó sì ń kẹ́dùn níwájú wọn. Bí wọ́n bá bi ọ́ pé kí ló dé tí o fi ń mí ìmí ẹ̀dùn, sọ fún wọn pé nítorí ìròyìn tí o gbọ́ ni. Nígbà tí ó bá ṣẹlẹ̀, ọkàn gbogbo eniyan yóo dàrú, ọwọ́ wọn yóo rọ ìrẹ̀wẹ̀sì yóo dé bá wọn, ẹsẹ̀ wọn kò ní ranlẹ̀ mọ́. Wò ó! Yóo ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, n óo sì mú un ṣẹ. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé èmi: OLUWA Ọlọrun ní: Ẹ wo idà, àní idà tí a ti pọ́n, tí a sì ti fi epo pa. A ti pọ́n ọn láti fi paniyan; a ti fi epo pa á, kí ó lè máa kọ mànà bíi mànàmáná. Ọ̀rọ̀ yìí kìí ṣe ọ̀rọ̀ àríyá; nítorí àwọn eniyan mi kọ̀, wọn kò náání ìkìlọ̀ ati ìbáwí mi. Nítorí náà, a pọ́n idà náà, a sì fi epo pa á, kí á lè fi lé ẹni tí yóo fi paniyan lọ́wọ́. Ìwọ ọmọ eniyan, kígbe, kí o sì pohùnréré ẹkún, nítorí àwọn eniyan mi ni a yọ idà sí; ati àwọn olórí ní Israẹli. Gbogbo wọn ni a óo fi idà pa pẹlu àwọn eniyan mi. Nítorí náà káwọ́ lérí kí o sì máa hu. Mò ń dán àwọn eniyan mi wò, bí wọ́n bá sì kọ̀, tí wọn kò ronupiwada, gbogbo nǹkan wọnyi yóo ṣẹlẹ̀ sí wọn, Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “Nítorí náà, ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀, kí o sápẹ́, fi idà lalẹ̀ léraléra, idà tí a fà yọ tí a fẹ́ fi paniyan. Idà tí yóo pa ọ̀pọ̀ eniyan ní ìpakúpa, tí ó sì súnmọ́ tòsí wọn pẹ́kípẹ́kí. Kí àyà wọn lè já, kí ọpọlọpọ lè kú ní ẹnubodè wọn. Mo ti fi idà tí ń dán lélẹ̀ fún pípa eniyan, ó ń kọ mànà bíi mànàmáná, a sì ti fi epo pa á. Máa pa wọ́n lọ ní ọwọ́ ọ̀tún, ati ní ọwọ́ òsì, níbikíbi tí ó bá sá ti kọjú sí. Èmi náà yóo máa pàtẹ́wọ́, inú tí ń bí mi yóo sì rọ̀, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, la ọ̀nà meji fún idà ọba Babiloni láti gbà wọ̀lú, kí ọ̀nà mejeeji wá láti ilẹ̀ kan náà. Fi atọ́ka sí oríta níbi tí ọ̀nà ti yà wọ ìlú. La ọ̀nà fún idà kan láti gbà wọ ìlú Raba ní ilẹ̀ Amoni, kí o sì la ọ̀nà mìíràn fún idà láti gbà wọ ilẹ̀ Juda ati ìlú Jerusalẹmu tí a mọ odi yíká. Nítorí pé ọba Babiloni ti dúró sí oríta, ní ibi tí ọ̀nà ti pínyà; ó dúró láti ṣe àyẹ̀wò. Ó mi ọfà, ó bá oriṣa sọ̀rọ̀, ó sì woṣẹ́ lára ẹ̀dọ̀ ẹran. Ọfà ìbò Jerusalẹmu yóo bọ́ sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀. Yóo kígbe, àwọn eniyan náà yóo sì kígbe sókè. Wọn óo gbé igi tí wọ́n fi ń fọ́ ìlẹ̀kùn ti ìlẹ̀kùn bodè rẹ̀, wọn yóo mọ òkítì sí ara odi rẹ̀, wọn yóo sì mọ ilé ìṣọ́ tì í. Gbogbo ohun tí ó ń ṣe yóo dàbí ẹni tí ń dífá irọ́ lójú àwọn ará ìlú, nítorí pé majẹmu tí wọ́n ti dá yóo ti kì wọ́n láyà; ṣugbọn ọba Babiloni yóo mú wọn ranti ẹ̀ṣẹ̀ wọn, yóo ṣẹgun wọn yóo sì kó wọn lọ. Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun, ní, ẹ ti jẹ́ kí n ranti ẹ̀ṣẹ̀ yín, nítorí pé ẹ ti tú àṣírí ẹ̀ṣẹ̀ yín, ninu gbogbo ohun tí ẹ̀ ń ṣe ni ẹ̀ṣẹ̀ yín ti hàn; ogun yóo ko yín nítorí pé ẹ ti mú kí n ranti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín. “Ìwọ olórí Israẹli, aláìmọ́ ati ẹni ibi, ọjọ́ rẹ pé; àkókò ìjìyà ìkẹyìn rẹ sì ti tó. Ẹ ṣí fìlà, kí ẹ sì ṣí adé ọba kúrò lórí, gbogbo nǹkan kò ní wà bí wọ́n ṣe rí. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Ẹ gbé àwọn tí ipò wọn rẹlẹ̀ ga, kí ẹ sì rẹ àwọn tí ipò wọn wà lókè sílẹ̀. Ìparun! Ìparun! N óo pa ìlú yìí run ni; ṣugbọn n kò ní tíì pa á run, títí ẹni tí ó ni í yóo fi dé, tí n óo sì fi lé e lọ́wọ́. “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun sọ nípa àwọn ará Amoni ati ẹ̀gàn wọn nìyí: ‘A ti fa idà yọ, láti paniyan. A ti fi epo pa á kí ó lè máa dán, kí ó sì máa kọ mànà bíi mànàmáná. Nígbà tí wọn ń ríran èké, tí wọ́n sì ń woṣẹ́ irọ́ fún ọ, a óo gbé idà náà lé ọrùn àwọn aláìmọ́ ati ẹni ibi, tí ọjọ́ wọn ti pé, àní ọjọ́ ìjìyà ìkẹyìn wọn. “ ‘Dá idà náà pada sinu àkọ̀ rẹ̀. Ní ilẹ̀ rẹ ní ibi tí a ti dá ọ, ni n óo ti dá ọ lẹ́jọ́. N óo bínú sí ọ lọpọlọpọ, ìrúnú mi yóo jó ọ bí iná, n óo fà ọ́ lé àwọn oníjàgídíjàgan lọ́wọ́, àwọn tí wọ́n mọ̀ bí wọ́n ṣe ń panirun. O óo di nǹkan ìdáná, lórí ilẹ̀ yín ni a óo pa yín sí, ẹ óo sì di ẹni ìgbàgbé, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ” OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, ṣé o óo dájọ́, ṣé o óo dájọ́ ìlú tí ó kún fún ìpànìyàn yìí? Sọ gbogbo ìwà ìríra rẹ̀ fún un. Sọ fún un pé èmi OLUWA Ọlọrun ní, ìwọ ìlú tí wọ́n ti ń paniyan ní ìpakúpa kí àkókò ìjìyà rẹ̀ lè tètè dé, ìlú tí ń fi oriṣa ba ara rẹ̀ jẹ́! A ti dá ọ lẹ́bi nítorí àwọn eniyan tí o pa, o sì ti di aláìmọ́ nítorí àwọn ère tí o gbẹ́. O ti mú kí ọjọ́ ìjìyà rẹ súnmọ́ tòsí, ọdún tí a dá fún ọ sì pé tán. Nítorí náà, mo ti sọ ọ́ di ẹni ẹ̀gàn láàrin àwọn eniyan, ati ẹni yẹ̀yẹ́ lójú gbogbo orílẹ̀-èdè. Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n súnmọ́ ọ ati àwọn tí wọ́n jìnnà sí ọ yóo máa fi ọ́ ṣe yẹ̀yẹ́, ìwọ tí o kò níyì, tí o kún fún ìdàrúdàpọ̀. Wo àwọn olórí ní ilẹ̀ Israẹli tí wọ́n wà ninu rẹ, olukuluku ti pinnu láti máa lo agbára rẹ̀ láti máa paniyan. Àwọn ọmọ kò náání baba ati ìyá wọn ninu rẹ; wọ́n sì ń ni àwọn àjèjì ninu rẹ lára; wọ́n sì ń fìyà jẹ àwọn aláìníbaba ati opó. O kò bìkítà fún àwọn ohun mímọ́ mi, o sì ti ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́. Àwọn eniyan inú rẹ ń parọ́ láti paniyan. Wọ́n ń jẹbọ kiri lórí àwọn òkè ńláńlá, wọ́n sì ń ṣe ohun ìtìjú. Àwọn mìíràn ń bá aya baba wọn lòpọ̀, wọ́n sì ń fi ipá bá obinrin lòpọ̀ ní ìgbà tí ó ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀ lọ́wọ́. Ẹnìkínní ń bá aya ẹnìkejì rẹ̀ lòpọ̀; àwọn kan ń bá aya ọmọ wọn lòpọ̀; ẹ̀gbọ́n ń bá àbúrò rẹ̀ lòpọ̀, àwọn mìíràn sì ń bá ọbàkan wọn lòpọ̀ ninu rẹ, Jerusalẹmu. Wọ́n ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti paniyan láàrin ìlú, wọ́n ń gba owó èlé, ẹ̀ ń ní àníkún, ẹ sì ń fi ipá gba owó lọ́wọ́ aládùúgbò yín, ẹ ti gbàgbé mi, èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “Nítorí náà mo pàtẹ́wọ́ le yín lórí nítorí èrè aiṣootọ tí ẹ̀ ń jẹ ati eniyan tí ẹ̀ ń pa ninu ìlú. Ǹjẹ́ o lè ní ìgboyà ati agbára ní ọjọ́ tí n óo bá jẹ ọ́ níyà. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni n óo sì ṣe. N óo fọn yín káàkiri ààrin àwọn àjèjì; n óo tu yín ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, n óo fi òpin sí ìwà èérí tí ẹ̀ ń hù ní Jerusalẹmu. N óo di ẹni ìdọ̀tí lójú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn nítorí rẹ, o óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan; àwọn ọmọ Israẹli ti di ìdàrọ́ lójú mi. Wọ́n dàbí idẹ, páànù, irin, ati òjé tí ó wà ninu iná alágbẹ̀dẹ. Wọ́n dàbí ìdàrọ́ ara fadaka. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní níwọ̀n ìgbà tí gbogbo yín ti di ìdàrọ́, n óo ko yín jọ sí ààrin Jerusalẹmu. Bí eniyan ṣe ń kó fadaka, idẹ, irin, òjé ati páànù pọ̀ sinu ìkòkò lórí iná alágbẹ̀dẹ, kí wọ́n lè yọ́, bẹ́ẹ̀ ni n óo fi ibinu ati ìrúnú ko yín jọ n óo sì yọ yín. N óo ko yín jọ, n óo fẹ́ ìrúnú mi si yín lára bí iná, ẹ óo sì yọ́. Bí wọn tí ń yọ́ fadaka ninu iná alágbẹ̀dẹ, bẹ́ẹ̀ ni n óo fi ibinu yọ yín, ẹ óo sì mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo bínú si yín.” OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé ilẹ̀ tí kò mọ́ ni ilẹ̀ wọn, ilẹ̀ tí òjò kò rọ̀ sí lákòókò ibinu èmi OLUWA. Àwọn olórí tí wọ́n wà nílùú dàbí kinniun tí ń bú, tí ó sì ń fa ẹran ya. Wọ́n ti jẹ àwọn eniyan run, wọ́n ń fi ipá já ohun ìní ati àwọn nǹkan olówó iyebíye gbà, wọ́n ti sọ ọpọlọpọ obinrin di opó nílùú. Àwọn alufaa rẹ̀ ti kọ òfin mi sílẹ̀, wọ́n ti sọ ibi mímọ́ mi di aláìmọ́. Wọn kò fi ìyàtọ̀ sáàrin àwọn nǹkan mímọ́ ati nǹkan àìmọ́; wọn kò sì kọ́ àwọn eniyan ní ìyàtọ̀ tí ó wà láàrin nǹkan mímọ́ ati àìmọ́. Wọn kò bìkítà fún ọjọ́ ìsinmi mi, mo sì ti di aláìmọ́ láàrin wọn. Àwọn olórí tí ó wà ninu wọn dàbí ìkookò tí ń fa ẹran ya, wọ́n ń pa eniyan, wọ́n sì ń run eniyan láti di olówó. Àwọn wolii wọn ń tàn wọ́n, wọ́n ń ríran irọ́, wọ́n ń woṣẹ́ èké. Wọ́n ń wí pé, OLUWA sọ báyìí, báyìí; bẹ́ẹ̀ sì ni OLUWA kò sọ nǹkankan. Àwọn eniyan ilẹ̀ náà ń fi ipá gba nǹkan-oní-nǹkan; wọ́n ń ni talaka ati aláìní lára, wọ́n sì ń fi ipá gba nǹkan lọ́wọ́ àwọn àlejò láì ṣe àtúnṣe. Mo wá ẹnìkan láàrin wọn tí ìbá tún odi náà mọ, kí ó sì dúró níbi tí odi ti ya níwájú mi láti bẹ̀bẹ̀ fún ilẹ̀ náà, kí n má baà pa á run, ṣugbọn n kò rí ẹnìkan. Nítorí náà, n óo bínú sí wọn; n óo fi ìrúnú pa wọ́n rẹ́, n óo sì gbẹ̀san ìwà wọn lára wọn. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, àwọn ọmọbinrin meji kan wà, tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìyá kan náà. Wọ́n lọ ṣe aṣẹ́wó ní ilẹ̀ Ijipti nígbà tí wọ́n jẹ́ ọmọge. Àwọn kan fọwọ́ fún wọn lọ́mú, wọ́n fọwọ́ pa orí ọmú wọn nígbà tí wọn kò tíì mọ ọkunrin. Orúkọ ẹ̀gbọ́n ń jẹ́ Ohola, ti àbúrò sì ń jẹ́ Oholiba. Àwọn mejeeji di tèmi; wọ́n sì bímọ lọkunrin ati lobinrin. Èyí tí ń jẹ́ Ohola ni Samaria, èyí tí ń jẹ́ Oholiba ni Jerusalẹmu. Ohola tún lọ ṣe àgbèrè lẹ́yìn tí ó ti di tèmi, ó tún ń ṣẹ́jú sí àwọn ará Asiria, olólùfẹ́ rẹ̀: àwọn ọmọ ogun tí wọn ń wọ aṣọ àlàárì, àwọn gomina ati àwọn ọ̀gágun, ati àwọn ẹlẹ́ṣin, ọdọmọkunrin ni gbogbo wọn, ojú wọn sì fanimọ́ra. Ó bá gbogbo àwọn eniyan pataki pataki Asiria ṣe àgbèrè, ó sì fi oriṣa gbogbo àwọn tí ó ń ṣẹ́jú sí ba ara rẹ̀ jẹ́. Kò kọ ìwà àgbèrè rẹ̀ tí ó ń hù nígbà tí ó ti wà ní ilẹ̀ Ijipti sílẹ̀. Nígbà èwe rẹ̀, àwọn ọkunrin bá a lòpọ̀, wọ́n fọwọ́ pa á lọ́mú, wọ́n sì tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn lọ́rùn lára rẹ̀. Nítorí gbogbo èyí, mo fi lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, àwọn ará Asiria tí ó ń ṣẹ́jú sí. Wọ́n tú aṣọ lára rẹ̀, wọ́n kó àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin; wọ́n sì fi idà pa òun alára. Orúkọ rẹ̀ wá di yẹ̀yẹ́ láàrin àwọn obinrin nígbà tí ìdájọ́ dé bá a. “Oholiba, àbúrò rẹ̀ rí èyí, sibẹsibẹ, ojú ṣíṣẹ́ sí ọkunrin ati àgbèrè tirẹ̀ burú ju ti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ. Ó ń ṣẹ́jú sí àwọn ará Asiria: àwọn gomina ati àwọn ọ̀gágun, àwọn ọmọ ogun tí wọ́n di ihamọra, tí wọn ń gun ẹṣin, ọdọmọkunrin ni gbogbo wọn, ojú wọn fanimọ́ra. Mo rí i pé ó ti ba ara rẹ̀ jẹ́, ọ̀nà kan náà ni àwọn mejeeji jọ ń tọ̀. “Ṣugbọn ìwà àgbèrè tirẹ̀ ju ti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ. Nígbà tí ó rí àwòrán àwọn ọkunrin, ará Kalidea tí a fi ọ̀dà pupa kùn lára ògiri, tí wọ́n di àmùrè, tí wọ́n wé lawani gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀, tí gbogbo wọn dàbí ọ̀gá àwọn oníkẹ̀kẹ́ ogun, àwọn ọmọ ogun ará Babilonia. Bí ó ti rí wọn, wọ́n wọ̀ ọ́ lójú, ó bá rán ikọ̀ sí wọn ní ilẹ̀ Kalidea. Àwọn ará Babiloni bá tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bá a ṣeré ìfẹ́ lórí ibùsùn rẹ̀, wọ́n sì fi ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn bà á jẹ́. Nígbà tí wọ́n bà á jẹ́ tán, ó kúrò lọ́dọ̀ wọn pẹlu ìríra. Nígbà tí ó ń ṣe àgbèrè ní gbangba, tí ó sì tú ara rẹ̀ sí ìhòòhò, mo yipada kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ pẹlu ìríra, bí mo ti yipada kúrò lọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Sibẹ ó tún fi kún ìwà àgbèrè rẹ̀, nígbà tí ó ranti àgbèrè ìgbà èwe rẹ̀ ní ilẹ̀ Ijipti. Ó kún fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ fún àwọn ọkunrin tí ojú ara wọn dàbí ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, nǹkan ọkunrin wọn sì dàbí ti ẹṣin.” O tún fẹ́ láti máa ṣe ìṣekúṣe tí o ṣe nígbà èwe rẹ, tí àwọn ọkunrin Ijipti ń dì mọ́ ọ lẹ́gbẹ̀ẹ́, tí wọ́n sì ń fi ọwọ́ fún ọ ní ọmú ọmọge. Nítorí náà, Oholiba, OLUWA Ọlọrun ní, “Mo ṣetán tí n óo gbé àwọn olùfẹ́ rẹ dìde, àwọn tí o kọ̀ sílẹ̀ nítorí ìríra. N óo mú wọn dojú kọ ọ́ ní gbogbo ọ̀nà: àwọn ará Babiloni ati gbogbo àwọn ará Kalidea láti Pekodi, ati Ṣoa ati Koa, pẹlu gbogbo àwọn ará Asiria: àwọn ọdọmọkunrin tí ojú wọn fanimọ́ra, àwọn gomina, ati àwọn ọ̀gágun, tí gbogbo wọn jẹ́ olórí ogun, tí wọ́n sì ń gun ẹṣin. Wọn óo dojú kọ ọ́ láti ìhà àríwá, pẹlu kẹ̀kẹ́ ogun, kẹ̀kẹ́ ẹrù, ati ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun. Wọn óo gbógun tì ọ́ ní gbogbo ọ̀nà pẹlu apata, asà ati àkẹtẹ̀ ogun. N óo fi ìdájọ́ rẹ lé wọn lọ́wọ́, òfin ilẹ̀ wọn ni wọn óo sì tẹ̀lé tí wọn óo fi dá ọ lẹ́jọ́. N óo dojú kọ ọ́ pẹlu ibinu, n óo jẹ́ kí wọ́n fi ìrúnú bá ọ jà. Wọn óo gé ọ ní etí ati imú, wọn óo sì fi idà pa àwọn eniyan rẹ tí wọ́n kù. Wọn óo kó àwọn ọmọ rẹ ọkunrin ati obinrin lọ, wọn óo sì dáná sun àwọn tí wọ́n kù. Wọn yóo bọ́ aṣọ lára rẹ; wọn yóo kó gbogbo nǹkan ọ̀ṣọ́ rẹ lọ. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe fi òpin sí ìṣekúṣe ati àgbèrè tí o kó ti ilẹ̀ Ijipti wá. O kò ní ṣíjú wo àwọn ará Ijipti mọ́, o kò sì ní ranti wọn mọ́.” OLUWA ní, “Mo ṣetán tí n óo fi ọ́ lé àwọn tí o kórìíra lọ́wọ́, àwọn tí ọkàn rẹ yipada kúrò lọ́dọ̀ wọn pẹlu ìríra. Ìkórìíra ni wọn yóo fi máa bá ọ gbé, wọn yóo kó gbogbo èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ lọ, wọn yóo sì fi ọ́ sílẹ̀ ní ìhòòhò goloto. Wọn yóo tú ọ sí ìhòòhò, gbogbo ayé yóo sì mọ̀ pé aṣẹ́wó ni ọ́. Ìṣekúṣe ati àgbèrè rẹ ni ó mú èyí wá sórí rẹ, nítorí o ti bá àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ṣe àgbèrè, o sì ti fi oriṣa wọn ba ara rẹ jẹ́. Ìwà tí ẹ̀gbọ́n rẹ hù ni ìwọ náà ń hù, nítorí náà, ìyà tí mo fi jẹ ẹ̀gbọ́n rẹ ni n óo fi jẹ ìwọ náà.” OLUWA Ọlọrun ní: “ọpọlọpọ ìyà tí mo fi jẹ ẹ̀gbọ́n rẹ ni n óo fi jẹ ọ́, wọn óo fi ọ́ rẹ́rìn-ín, wọn óo sì fi ọ́ ṣẹ̀sín, nítorí ìyà náà óo pọ̀. Ìyà óo jẹ ọ́ lọpọlọpọ, ìbànújẹ́ óo sì dé bá ọ. N óo mú ìpayà ati ìsọdahoro bá ọ, bí mo ṣe mú un bá Samaria, ẹ̀gbọ́n rẹ. O óo jìyà ní àjẹtẹ́rùn, tóbẹ́ẹ̀ tí o óo máa fi àkúfọ́ àwo ìyà tí o bá jẹ ya ara rẹ lọ́mú. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “Nítorí pé o ti gbàgbé mi, o sì ti kọ̀ mí sílẹ̀, o óo jìyà ìṣekúṣe ati àgbèrè rẹ.” OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan ṣé o óo dá ẹjọ́ Ohola ati Oholiba? Nítorí náà fi ìwà ìríra tí wọ́n hù hàn wọ́n. Nítorí wọ́n ti ṣe àgbèrè, wọ́n sì ti paniyan; wọ́n ṣe àgbèrè ẹ̀sìn lọ́dọ̀ àwọn oriṣa wọn, wọ́n sì ti pa àwọn ọmọ wọn ọkunrin tí wọ́n bí fún mi, bọ oriṣa wọn. Èyí nìkan kọ́ ni wọ́n ṣe sí mi, wọ́n sọ ibi mímọ́ mi di eléèérí, wọ́n sì ba àwọn ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́. Ní ọjọ́ náà gan-an tí wọ́n pa àwọn ọmọ wọn, tí wọ́n fi wọ́n rúbọ sí oriṣa wọn, ni wọ́n tún wá sí ilé ìsìn mi, tí wọ́n sọ ọ́ di eléèérí. Wò ó! Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ní ilé mi. “Wọ́n tilẹ̀ tún ranṣẹ lọ pe àwọn ọkunrin wá láti òkèèrè, oníṣẹ́ ni wọ́n gbé dìde kí ó lọ pè wọ́n wá; àwọn náà sì wá. Nígbà tí wọ́n dé, ẹ wẹ̀, ẹ kun àtíkè, ẹ tọ́ ojú, ẹ sì ṣe ara yín lọ́ṣọ̀ọ́. Ẹ jókòó lórí àga ọlọ́lá. Ẹ tẹ́ tabili siwaju; ẹ wá gbé turari ati òróró mi lé e lórí. Ogunlọ́gọ̀ àwọn aláìbìkítà ẹ̀dá bẹ̀rẹ̀ sí pariwo lọ́dọ̀ yín, àwọn ọkunrin ọ̀mùtí lásánlàsàn kan sì wá láti inú aṣálẹ̀, wọ́n kó ẹ̀gbà sí àwọn obinrin lọ́wọ́, wọ́n fi adé tí ó lẹ́wà dé wọn lórí. Nígbà náà ni mo wí lọ́kàn ara mi pé, Ǹjẹ́ àwọn ọkunrin wọnyi kò tún ń ṣe àgbèrè, pẹlu àwọn obinrin panṣaga burúkú yìí? Nítorí wọ́n ti tọ̀ wọ́n lọ bí àwọn ọkunrin tí ń tọ aṣẹ́wó lọ. Wọ́n wọlé tọ Ohola ati Oholiba lọ, wọ́n sì bá wọn ṣe àgbèrè. Ṣugbọn àwọn olódodo eniyan ni yóo dá àwọn obinrin náà lẹ́jọ́ panṣaga, ati ti apànìyàn, nítorí pé panṣaga eniyan ni wọ́n, wọ́n sì ti paniyan.” Nítorí pé OLUWA Ọlọrun ní, “Ẹ pe ogunlọ́gọ̀ eniyan lé wọn lórí kí wọ́n ṣẹ̀rù bà wọ́n, kí wọ́n sì kó wọn lẹ́rù; kí ogunlọ́gọ̀ eniyan wọnyi óo sọ wọ́n lókùúta, wọn óo sì gún wọn ní idà. Wọn óo pa àwọn ọmọ wọn; tọkunrin tobinrin, wọn óo sì dáná sun ilé wọn. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe fi òpin sí ìṣekúṣe ní ilẹ̀ náà; èyí óo sì kọ́ gbogbo àwọn obinrin lẹ́kọ̀ọ́, pé kí wọ́n má máa ṣe ìṣekúṣe bíi tiyín. N óo da èrè ìṣekúṣe yín le yín lórí, ẹ óo sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà yín. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun.” OLUWA bá mi sọ̀rọ̀ ní ọjọ́ kẹwaa, oṣù kẹwaa, ọdún kẹsan-an tí a ti wà ní ìgbèkùn, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, sàmì sí ọjọ́ òní, kọ orúkọ ọjọ́ òní sílẹ̀. Lónìí gan-an ni ọba Babilonia gbógun ti Jerusalẹmu. Pa òwe yìí fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọnyi kí o sì wí fún wọn pé, ní orúkọ èmi OLUWA Ọlọrun: Gbé ìkòkò kaná; bu omi sí i. Kó ègé ẹran sí i, gbogbo ibi tí ó dára jùlọ lára ẹran, ẹran itan ati ti èjìká, kó egungun tí ó dára náà sí i kí ó kún. Ẹran tí ó dára jùlọ ninu agbo ni kí o mú, kó igi jọ sí abẹ́ ìkòkò náà, kí o bọ ẹran náà, bọ̀ ọ́ teegunteegun.” Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní: “Ègbé ni fún ìlú apànìyàn, ìkòkò tí inú rẹ̀ dípẹtà, tí ìdọ̀tí rẹ̀ kò ṣí kúrò ninu rẹ̀! Yọ ẹran inú rẹ̀ kúrò lọ́kọ̀ọ̀kan, sá máa mú èyí tí ọwọ́ rẹ bá ti bà. Nítorí pé ẹ̀jẹ̀ eniyan tí ó pa wà ninu rẹ̀, orí àpáta ni ó da ẹ̀jẹ̀ wọn sí, kò dà á sórí ilẹ̀, tí yóo fi rí erùpẹ̀ bò ó. Mo ti da ẹ̀jẹ̀ tí ó ta sílẹ̀ sórí àpáta, kí ó má baà ṣe é bò mọ́lẹ̀. Kí inú lè bí mi, kí n lè gbẹ̀san.” Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní: “Ègbé ni fún ìlú tí ó kún fún ìpànìyàn yìí, èmi fúnra mi ni n óo kó iná ńlá jọ. Ẹ kó ọpọlọpọ igi jọ; ẹ ṣáná sí i. Ẹ se ẹran náà dáradára, ẹ da omi rẹ̀ nù, kí ẹ jẹ́ kí egungun rẹ̀ jóná. Lẹ́yìn náà, ẹ gbé òfìfo ìkòkò náà léná, kí ó gbóná, kí idẹ inú rẹ̀ lè yọ́; kí ìdọ̀tí tí ó wà ninu rẹ̀ lè jóná, kí ìpẹtà rẹ̀ sì lè jóná pẹlu. Lásán ni mò ń ṣe wahala, gbogbo ìpẹtà náà kò ní jóná. Jerusalẹmu, ìṣekúṣe ti dípẹtà sinu rẹ, mo fọ̀ ọ́ títí, ìdọ̀tí kò kúrò ninu rẹ, kò sì ní kúrò mọ́ títí n óo fi bínú sí ọ tẹ́rùn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, n óo sì mú un ṣẹ. Bí mo ti wí ni n óo ṣe, n kò ní dáwọ́ dúró, n kò ní dá ẹnikẹ́ni sí, n kò sì ní yí ọkàn pada. Ìwà ati ìṣe yín ni n óo fi da yín lẹ́jọ́. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, wò ó! Mo ṣetán tí n óo gba ohun tí ń dùn ọ́ ninu lọ́wọ́ rẹ. Lójijì ni n óo gbà á, o kò sì gbọdọ̀ banújẹ́ tabi kí o sọkún, bẹ́ẹ̀ ni omi kò gbọdọ̀ kán sílẹ̀ lójú rẹ. O lè mí ìmí ẹ̀dùn, ṣugbọn a kò gbọdọ̀ gbọ́ ohùn rẹ, o kò sì gbọdọ̀ ṣọ̀fọ̀. Wé lawani mọ́rí, sì wọ bàtà. O kò gbọdọ̀ fi aṣọ bo ẹnu, o kò sì gbọdọ̀ jẹ oúnjẹ ọlọ́fọ̀.” Mo bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀ láàárọ̀, nígbà tí ó di àṣáálẹ́, iyawo mi kú. Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ keji mọ́, mo ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ pé kí n ṣe. Àwọn eniyan bá bi mí pé, “Ṣé kò yẹ kí o sọ ohun tí nǹkan tí ó ń ṣẹlẹ̀ yìí túmọ̀ sí fún wa, tí o fi ń ṣe báyìí.” Mo bá sọ fún wọn pé, “OLUWA ni ó bá mi sọ̀rọ̀, tí ó ní kí n sọ fún ẹ̀yin ọmọ Israẹli pé òun OLUWA sọ pé òun óo sọ ibi mímọ́ òun di aláìmọ́: ibi mímọ́ òun tí ẹ fi ń ṣògo, tí ó jẹ́ agbára yín, tí ẹ fẹ́ràn láti máa wò, tí ọkàn yín sì fẹ́. Ogun yóo pa àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin yín tí ẹ fi sílẹ̀. Bí mo ti ṣe yìí gan-an ni ẹ̀yin náà gbọdọ̀ ṣe, ẹ kò gbọdọ̀ fi aṣọ bo ẹnu yín tabi kí ẹ máa jẹ oúnjẹ ọlọ́fọ̀. Lawani yín gbọdọ̀ wà lórí yín; kí bàtà yín sì wà ní ẹsẹ̀ yín, ẹ kò gbọdọ̀ ṣọ̀fọ̀ tabi kí ẹ sọkún. Ẹ óo joró nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín, ẹ óo sì máa bá ara yín sọ̀rọ̀ tẹ̀dùntẹ̀dùn. Ó ní èmi Isikiẹli óo jẹ́ àmì fun yín, gbogbo bí mo bá ti ṣe ni ẹ̀yin náà gbọdọ̀ ṣe nígbà tí ọ̀rọ̀ yìí bá ṣẹlẹ̀. Ẹ óo sì mọ̀ pé òun ni OLUWA Ọlọrun.” OLUWA ní, “Ìwọ ní tìrẹ, ọmọ eniyan, ní ọjọ́ tí mo bá gba ibi ààbò wọn lọ́wọ́ wọn, àní ayọ̀ ati ògo wọn, ohun tí wọ́n fẹ́ máa rí, tí ọkàn wọn sì fẹ́, pẹlu àwọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin, ní ọjọ́ náà, ẹnìkan tí yóo sá àsálà ni yóo wá fún ọ ní ìròyìn. Ní ọjọ́ náà, ẹnu rẹ óo yà, o óo sì le sọ̀rọ̀; o kò ní ya odi mọ́. Ìwọ ni o óo jẹ́ àmì fún wọn; wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú sí àwọn ará Amoni kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wọn. Wí fún wọn báyìí pé, ‘Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA Ọlọrun wí; nítorí pé ẹ̀ ń yọ̀ nígbà tí wọ́n sọ ibi mímọ́ mi di aláìmọ́, ati pé ẹ̀ ń yọ ilẹ̀ Israẹli, nígbà tí wọ́n sọ ọ́ di ahoro, ẹ sì ń yọ ilẹ̀ Juda, nígbà tí wọ́n kó o lọ sí ìgbèkùn; nítorí náà, n óo fà yín lé àwọn ará ilẹ̀ ìlà oòrùn lọ́wọ́, ẹ óo sì di tiwọn. Wọn óo pa àgọ́ sí ààrin yín; wọn óo tẹ̀dó sí ààrin yín; wọn óo máa jẹ èso oko yín, wọn óo sì máa mu wàrà yín. N óo sọ ìlú Raba di pápá àwọn ràkúnmí, àwọn ìlú Amoni yóo sì di pápá ẹran. Wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA!’ Nitori báyìí ni OLUWA Ọlọrun wí, “Ẹ̀yin ń pàtẹ́wọ́, ẹ̀ ń fò sókè, ẹ sì ń yọ àwọn ọmọ Israẹli. Nítorí náà, ẹ wò ó! Mo ti nawọ́ ìyà si yín, n óo sì fi yín ṣe ìkógun fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. N óo pa yín run láàrin àwọn eniyan ilẹ̀ ayé, n óo sì pa yín rẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” OLUWA Ọlọrun ní, “Àwọn ará Moabu ń wí pé ilẹ̀ Juda dàbí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, nítorí náà, n óo tú àwọn ìlú Moabu tí wọ́n wà ní apá ọ̀tún ati apá òsì ká: àwọn ìlú tí ó dára jù ní ilẹ̀ Moabu, Beti Jẹṣimoti, Baali Meoni ati Kiriataimu ká. N óo fún àwọn ará ìlà oòrùn ní òun ati ilẹ̀ Amoni, wọn óo di ìkógun, kí á má baà ranti rẹ̀ mọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè. N óo ṣe ìdájọ́ àwọn ará Moabu; wọn yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA!” OLUWA Ọlọrun ní, “Nítorí àwọn ará Edomu gbẹ̀san lára àwọn ará Juda, wọ́n sì ṣẹ̀ nítorí ẹ̀san tí wọ́n gbà. N óo nawọ́ ìyà sí Edomu, n óo pa ati eniyan ati ẹranko inú rẹ̀ run. N óo sọ ọ́ di ahoro láti Temani títí dé Dedani. Ogun ni yóo pa wọ́n. Àwọn eniyan mi, Israẹli, ni n óo lò láti gbẹ̀san lára Edomu. Bí inú ti bí mi tó, ati bí inú mi ṣe ń ru tó, ni wọn yóo ṣe fi ìyà jẹ Edomu. Wọn óo wá mọ̀ bí mo ti lè gbẹ̀san tó. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA Ọlọrun ní, “Àwọn ará Filistia gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá wọn, wọn sì fi ìkórìíra àtayébáyé pa wọ́n run, nítorí náà, n óo nawọ́ ìyà sí wọn, n óo pa àwọn ọmọ Kereti run, n óo pa àwọn tí ó kù sí etí òkun rẹ́. N óo gbẹ̀san lára wọn lọpọlọpọ; n óo fi ìrúnú fi ìyà ńlá jẹ wọ́n. Wọn óo wá mọ̀ nígbà tí mo bá gbẹ̀san lára wọn pé èmi ni OLUWA.” Ní ọjọ́ kinni oṣù, ní ọdún kọkanla tí a dé ìgbèkùn, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀: ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, nítorí pé àwọn ará ìlú Tire ń yọ̀ sí ìṣubú ìlú Jerusalẹmu, wọ́n ń sọ wí pé ìlẹ̀kùn ibodè àwọn eniyan yìí ti já, ibodè wọn sì ti ṣí sílẹ̀ fún wa, nisinsinyii tí ó di àlàpà, a óo ní àníkún. “Nítorí náà, mo lòdì sí ọ, ìwọ Tire, n óo sì kó ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè wá gbógun tì ọ́, bíi ríru omi òkun. Wọn óo wó odi Tire; wọn óo wó ilé-ìṣọ́ tí ó wà ninu rẹ̀ palẹ̀. N óo ha erùpẹ̀ inú rẹ̀ kúrò, n óo sì sọ ọ́ di àpáta lásán. Yóo di ibi tí wọn óo máa sá àwọ̀n sí láàrin òkun, nítorí èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀; yóo sì di ìkógun fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Ogun yóo kó àwọn ìlú kéékèèké tí ó wà ní gbogbo agbègbè tí ó yí i ká. Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.” OLUWA Ọlọrun ní, “Ẹ wò ó! N óo mú Nebukadinesari, ọba ńlá Babiloni wá, láti ìhà àríwá, yóo wá gbógun ti Tire. Nebukadinesari, ọba àwọn ọba óo wá, pẹlu ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin ati ọpọlọpọ ọmọ ogun. Yóo fi idà pa àwọn ará ìlú kéékèèké tí ó wà ní agbègbè tí ó yí ọ ká. Wọn óo mọ òkítì sí ara odi rẹ, wọn yóo ru erùpẹ̀ jọ, wọn óo fi la ọ̀nà lẹ́yìn odi rẹ, wọn óo sì fi asà borí nígbà tí wọ́n bá ń gun orí odi rẹ bọ̀. Wọn óo fi ìtì igi wó odi rẹ, wọn óo sì fi àáké wó ilé-ìṣọ́ rẹ lulẹ̀. Ẹṣin rẹ̀ óo pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí eruku ẹsẹ̀ wọn yóo bò ọ́ mọ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n bá dé ẹnubodè rẹ, ariwo àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ ati ti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù ati ti kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ yóo mi odi rẹ tìtì, nígbà tí wọ́n bá dé ẹnubodè rẹ, bí ìgbà tí àwọn ọmọ ogun bá wọ ìlú tí odi rẹ̀ ti wó. Yóo fi pátákò ẹsẹ̀ àwọn ẹṣin rẹ̀ tú gbogbo ilẹ̀ ìgboro rẹ, yóo fi idà pa àwọn eniyan rẹ; yóo sì wó àwọn òpó ńláńlá rẹ lulẹ̀. Yóo kó ọrọ̀ rẹ ati àwọn ọjà tí ò ń tà ní ìkógun. Yóo wó odi rẹ ati àwọn ilé dáradára tí ó wà ninu rẹ lulẹ̀. Yóo ru òkúta, ati igi, ati erùpẹ̀ tí ó wà ninu ìlú rẹ dà sinu òkun. N óo wá fi òpin sí orin kíkọ ninu rẹ; a kò sì ní gbọ́ ohùn dùùrù ninu rẹ mọ́. N óo sì sọ ọ́ di àpáta lásán, o óo di ibi tí wọn óo máa sá àwọ̀n sí; ẹnikẹ́ni kò sì ní tún ọ kọ́ mọ́. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA Ọlọrun sọ fún ìlú Tire pé, “Ǹjẹ́ gbogbo ilẹ̀ tí ó wà létí òkun kò ní mì tìtì nítorí ìṣubú rẹ, nígbà tí àwọn tí wọ́n farapa bá ń kérora, tí a sì pa ọpọlọpọ ní ìpakúpa ninu rẹ? Gbogbo àwọn ọba ìlú etí òkun yóo sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ wọn, wọn óo bọ́ aṣọ ìgúnwà wọn, ati agbádá ọlọ́nà tí wọ́n wọ̀, jìnnìjìnnì óo dà bò wọ́n, wọn óo jókòó sórí ilẹ̀, wọn óo bẹ̀rẹ̀ sí máa gbọ̀n, ẹnu óo sì yà wọ́n nítorí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ọ. Wọn yóo wá dá orin arò fún ọ pé: Wò ó bí o ti parẹ́ ninu òkun, ìwọ ìlú olókìkí, ìwọ ìlú tí ó lágbára lórí òkun, ìwọ ati àwọn tí ń gbé inú rẹ, àwọn tí wọn ń mú kí ẹ̀rù rẹ máa ba àwọn tí wọn ń gbé orí ilẹ̀. Àwọn erékùṣù yóo wárìrì ní ọjọ́ ìṣubú rẹ. Nítòótọ́, àwọn erékùṣù tí wọ́n wà ninu òkun yóo dààmú nítorí ìparun rẹ.” OLUWA Ọlọrun ní, “Nígbà tí mo bá sọ ọ́ di ìlú ìparun bí àwọn ìlú tí ẹnìkan kò gbé inú rẹ̀, nígbà tí mo bá mú kí omi òkun bò ọ́ mọ́lẹ̀, tí ibú omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀, n óo fà ọ́ lulẹ̀ lọ bá àwọn ẹni àtijọ́ tí wọ́n wà ninu ọ̀gbun. N óo mú kí o máa gbé ìsàlẹ̀ ilẹ̀ bí ìlú àwọn tí wọ́n ti ṣègbé nígbà àtijọ́, ati àwọn tí wọ́n ti lọ sinu ọ̀gbun; kí ẹnikẹ́ni má baà gbé inú rẹ mọ́, kí o má sì sí lórí ilẹ̀ alààyè mọ́. N óo mú òpin tí ó bani lẹ́rù dé bá ọ, o kò sì ní sí mọ́; bí ẹnikẹ́ni tilẹ̀ ń wá ọ, ẹnìkan kò ní rí ọ mọ́ títí lae. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, kọ orin arò nípa ìlú Tire. Sọ fún ìlú Tire tí ó wà ní etí òkun, tí ń bá gbogbo àwọn tí wọn ń gbé etí òkun ṣòwò. Sọ fún un pé OLUWA Ọlọrun ní: Tire, ìwọ tí ò ń sọ pé, o dára tóbẹ́ẹ̀, tí ẹwà rẹ kò kù síbìkan! Agbami òkun ni bodè rẹ. Àwọn tí wọ́n kọ́ ọ fi ẹwà jíǹkí rẹ. Igi firi láti Seniri ni wọ́n fi ṣe gbogbo ẹ̀gbẹ́ rẹ. Igi kedari láti Lẹbanoni ni wọ́n sì fi ṣe òpó ọkọ̀ rẹ. Igi oaku láti Baṣani ni wọ́n fi ṣe ajẹ̀ rẹ̀ Igi sipirẹsi láti erékùṣù Kipru ni wọ́n fi ṣe ilé rẹ. Wọ́n sì fi eyín erin bo inú rẹ̀. Aṣọ ọ̀gbọ̀ tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára láti ilẹ̀ Ijipti, ni wọ́n fi ṣe ìgbòkun rẹ tí ó dàbí àsíá ọkọ̀ rẹ. Aṣọ aláró ati aṣọ àlàárì láti etíkun Eliṣa ni wọ́n fi ṣe ìbòrí rẹ. Àwọn ará Sidoni ati Arifadi ni atukọ̀ rẹ. Àwọn ọlọ́gbọ́n láti ilẹ̀ Ṣemeri wà lọ́dọ̀ rẹ, àwọn ni wọ́n ń darí ọkọ̀ ojú omi rẹ. Àwọn àgbààgbà Gebali ati àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n oníṣẹ́ ọwọ́ wà lọ́dọ̀ rẹ, àwọn ni wọ́n ń fi ọ̀dà dí ọkọ̀ rẹ kí omi má baà wọnú rẹ̀. Gbogbo ọkọ̀ ojú omi ati àwọn tí ń tù wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ, wọ́n ń bá ọ ra ọjà. “Àwọn ará Pasia ati àwọn ará Ludi ati àwọn ará Puti wà láàrin àwọn ọmọ ogun rẹ bí akọni. Wọ́n gbé asà ati àṣíborí wọn kọ́ sinu rẹ, wọ́n jẹ́ kí o gba ògo. Àwọn ará Arifadi ati Heleki wà lórí odi rẹ yíká, àwọn ará Gamadi sì wà ninu àwọn ilé-ìṣọ́ rẹ. Wọ́n gbé asà wọn kọ́ káàkiri ara ògiri rẹ, àwọn ni wọ́n mú kí ẹwà rẹ pé. “Àwọn ará Taṣiṣi ń bá ọ rajà nítorí ọpọlọpọ ọrọ̀ rẹ: fadaka, irin, páànù ati òjé ni wọ́n fi ń ṣe pàṣípààrọ̀ ọjà lọ́dọ̀ rẹ. Àwọn ará Jafani, Tubali, ati Meṣeki ń bá ọ ṣòwò; wọ́n ń kó ẹrú ati ohun èlò idẹ wá fún ọ, wọn fi ń gba àwọn nǹkan tí ò ń tà. Àwọn ará Beti Togama a máa kó ẹṣin, ati ẹṣin ogun, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wá ṣe pàṣípààrọ̀ àwọn nǹkan tí ò ń tà. Àwọn ará Didani ń bá ọ ṣòwò, ọpọlọpọ etíkun ni ẹ tí ń tajà, wọ́n ń fi eyín erin ati igi Ẹboni ṣe pàṣípààrọ̀ fún ọ. Àwọn ará Edomu bá ọ ṣòwò nítorí ọpọlọpọ ọjà tí ò ń tà. Òkúta emeradi, aṣọ àlàárì, aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́ tẹ́ẹ́rẹ́, iyùn ati òkúta agate ni wọ́n fi ń ṣe pàṣípààrọ̀ fún ọ. Juda ati ilé Israẹli bá ọ ṣòwò: wọ́n ń kó ọkà, èso olifi, àkọ́so èso ọ̀pọ̀tọ́, oyin, òróró ati òrí wá láti fi ṣe pàṣípààrọ̀ àwọn nǹkan tí ò ń tà. Àwọn ará Damasku bá ọ ṣòwò nítorí ọpọlọpọ ọjà ati àwọn nǹkan olówó iyebíye tí ò ń tà, wọ́n mú ọtí waini ati irun aguntan funfun wá láti Heliboni. Àwọn ará Fedani ati Jafani láti Usali a máa wá fi ọtí waini pààrọ̀ ohun tí ò ń tà; wọn a kó àwọn nǹkan èlò irin wá, ati igi kasia. Àwọn ará Dedani náà ń bá ọ ṣòwò, wọ́n ń kó aṣọ gàárì tí wọ́n fi ń gun ẹṣin wá. Àwọn ará Arabia ati àwọn olóyè Kedari ni àwọn oníbàárà rẹ pataki, wọn a máa ra ọ̀dọ́ aguntan, àgbò, ati ewúrẹ́ lọ́wọ́ rẹ. Àwọn oníṣòwò Ṣeba ati ti Raama náà a máa bá ọ ra ọjà, oríṣìíríṣìí turari olóòórùn dídùn ati òkúta olówó iyebíye ati wúrà ni wọ́n fi ń ṣe pàṣípààrọ̀ ọjà lọ́wọ́ rẹ. Àwọn ará Harani, Kane, Edẹni, Aṣuri ati Kilimadi ń bá ọ ṣòwò. Wọ́n ń kó ojúlówó ẹ̀wù aṣọ aláwọ̀ aró wá tà fún ọ, ati aṣọ tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára, ati ẹni tí ó ní oríṣìíríṣìí àwọ̀, tí wọ́n fi ìko hun. Àwọn ọkọ̀ Taṣiṣi ní ń bá ọ ru ọjà rẹ lọ ta. Ọjà kún inú rẹ, ẹrù rìn ọ́ mọ́lẹ̀ láàrin omi òkun. Àwọn tí ń wà ọ́ ti tì ọ́ sí ààrin agbami òkun. Atẹ́gùn ńlá ti dà ọ́ nù láàrin agbami òkun. Gbogbo ọrọ̀ rẹ, ati gbogbo ọjà olówó iyebíye rẹ, àwọn tí ń tu ọkọ̀ rẹ ati àwọn tí ń darí rẹ; àwọn tí ń fi ọ̀dà dí ihò ara ọkọ̀ rẹ ati àwọn tí ń bá ọ ṣòwò. Gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ ati àwọn èrò tí ó wà ninu rẹ, ni yóo rì sí ààrin gbùngbùn òkun, ní ọjọ́ ìparun rẹ. Gbogbo èbúté yóo mì tìtì nígbà tí àwọn tí wọn ń tọ́ ọkọ̀ rẹ bá kígbe. Gbogbo àwọn atukọ̀ ni yóo jáde kúrò ninu ọkọ̀. Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ninu ọkọ̀ ati àwọn tí ń darí ọkọ̀ yóo dúró ní èbúté. Wọn óo gbé ohùn sókè sí ọ, wọn óo sun ẹkún kíkan kíkan. Wọn óo da erùpẹ̀ sórí wọn, wọn óo yíra mọ́lẹ̀ ninu eérú. Wọn óo fá irun orí wọn nítorí rẹ, wọn óo sán aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ìdí, wọn óo sì fi ìbànújẹ́ ọkàn sọkún nítorí rẹ, inú wọn yóo sì bàjẹ́. Bí wọ́n bá ti ń sọkún, wọn óo máa kọ orin arò nípa rẹ báyìí pé: ‘Ìlú wo ló tíì parun bíi Tire, láàrin òkun? Nígbà tí àwọn ọjà rẹ bá dé láti òkè òkun, ò ń tẹ́ ọpọlọpọ eniyan lọ́rùn. Ò ń fi ọpọlọpọ ọrọ̀ rẹ ati ọjà rẹ sọ àwọn ọba ayé di ọlọ́rọ̀. Wàyí ò, omi òkun ti fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́, o ti rì sí ìsàlẹ̀ òkun.’ Gbogbo àwọn ọjà rẹ ati àwọn tí ń wa ọkọ̀ rẹ ti rì pẹlu rẹ. “Ẹnu ya gbogbo àwọn tí ń gbé etí òkun nítorí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọ. Àwọn ọba wọn ń gbọ̀n jìnnìjìnnì, ẹ̀rù sì hàn ní ojú wọn. Àwọn oníṣòwò orílẹ̀-èdè ayé ń pòṣé lé ọ lórí. Òpin burúkú dé bá ọ, o kò ní sí mọ́ títí lae.” OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún ọba Tire pé OLUWA ní, ‘Nítorí pé ìgbéraga kún ọkàn rẹ, o sì ti sọ ara rẹ di oriṣa, o sọ pé o jókòó ní ibùjókòó àwọn oriṣa láàrin òkun; bẹ́ẹ̀ sì ni eniyan ni ọ́, o kì í ṣe oriṣa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ò ń rò pé o gbọ́n bí àwọn oriṣa, nítòótọ́, o gbọ́n ju Daniẹli lọ, kò sì sí ohun àṣírí kan tí ó ṣú ọ lójú. Nípa ọgbọ́n ati ìmọ̀ rẹ, o ti kó ọpọlọpọ ọrọ̀ jọ fún ara rẹ, o sì kó wúrà ati fadaka jọ sinu ilé ìṣúra rẹ. O ti ní àníkún ọrọ̀ nítorí ọgbọ́n rẹ ninu òwò ṣíṣe, ìgbéraga sì ti kún ọkàn rẹ nítorí ọrọ̀ rẹ.’ “Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Nítorí pé o ka ara rẹ kún ọlọ́gbọ́n bí àwọn oriṣa, n óo kó àwọn àjèjì wá bá ọ; àwọn tí wọ́n burú jù ninu àwọn orílẹ̀-èdè, wọn óo sì gbógun tì ọ́, wọ́n yóo sì ba ẹwà ati ògo rẹ jẹ́, pẹlu ọgbọ́n rẹ. Wọn óo tì ọ́ sinu ọ̀gbun; o óo sì kú ikú ogun láàrin omi òkun. Ṣé o óo lè sọ pé oriṣa kan ni ọ́ lójú àwọn tí wọ́n bá fẹ́ pa ọ́? Nígbà tí wọ́n bá ń ṣá ọ lọ́gbẹ́, ṣé eniyan ni o óo wá pe ara rẹ àbí oriṣa. Ikú aláìkọlà ni o óo kú lọ́wọ́ àwọn àjèjì, nítorí èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ” OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, kọ orin arò nítorí ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí ọba Tire. Wí fún un pé OLUWA Ọlọrun ní: ‘O ti jẹ́ àpẹẹrẹ ìwà pípé, o kún fún ọgbọ́n, o sì lẹ́wà tóbẹ́ẹ̀ tí o kò ní àbùkù kankan. O wà ninu Edẹni, ọgbà Ọlọrun. Gbogbo òkúta olówó iyebíye ni wọ́n fi ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́, àwọn òkúta bíi: kaneliani, topasi, ati jasiperi; kirisolite, bẹrili, ati onikisi; safire, kabọnku ati emeradi. A gbé ọ ka inú àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ wúrà tí a ṣe fún ọ ní ọjọ́ tí a dá ọ. Mo fi kerubu tí a fi àmì òróró yàn tì ọ́. O wà lórí òkè mímọ́ èmi Ọlọrun, o sì ń rìn láàrin àwọn òkúta olówó iyebíye tí ń tàn yinrinyinrin. O péye ninu gbogbo ọ̀nà rẹ, láti ọjọ́ tí wọ́n ti dá ọ títí di ìgbà tí a rí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ rẹ. Ninu ọpọlọpọ òwò tí ó ń ṣe, o bẹ̀rẹ̀ sí hu ìwà jàgídíjàgan, o sì dẹ́ṣẹ̀, nítorí náà mo lé ọ jáde bí ohun ìríra kúrò lórí òkè Ọlọrun. Kerubu tí ń ṣọ́ ọ sì lé ọ jáde kúrò láàrin àwọn òkúta olówó iyebíye tí ń tàn yinrinyinrin. Ọkàn rẹ kún fún ìgbéraga nítorí pé o lẹ́wà, o ba ọgbọ́n rẹ jẹ́ nítorí ògo rẹ. Mo bì ọ́ lulẹ̀, mo sọ ọ́ di ìran wíwò fún àwọn ọba. O ti fi ọpọlọpọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tí o dá nítorí ìwà aiṣootọ ninu òwò rẹ, ba ibi mímọ́ mi jẹ́. Nítorí náà, mo jẹ́ kí iná ṣẹ́ ní ààrin rẹ; ó sì jó ọ run; mo sì sọ ọ́ di eérú lórí ilẹ̀ ayé lójú gbogbo àwọn tí ń wò ọ́. Gbogbo àwọn tí wọ́n mọ̀ ọ́ láàrin àwọn eniyan láyé ni ó yà lẹ́nu nígbà tí wọ́n rí ọ. Òpin burúkú ti dé bá ọ, o kò sì ní sí mọ́ títí ayé.’ ” OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú rẹ sí Sidoni, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ pé OLUWA Ọlọrun ní, ‘Wò ó, mo lòdì sí ọ, ìwọ Sidoni. N óo sì fi ògo mi hàn láàrin rẹ. Wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá ṣe ìdájọ́ fún àwọn tí ń gbé inú rẹ; tí mo sì fi ìwà mímọ́ mi hàn wọ́n. Nítorí n óo fi àjàkálẹ̀ àrùn bá ọ jà n óo sì jẹ́ kí àgbàrá ẹ̀jẹ̀ máa ṣàn ní ìgboro rẹ. Àwọn tí wọ́n yí ọ ká yóo gbógun tì ọ́, wọn óo sì fi idà pa ọpọlọpọ eniyan ninu rẹ,’ nígbà náà o óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” OLUWA Ọlọrun ní, “Ní ti ilé Israẹli, kò ní sí ọ̀tá tí yóo máa ṣe ẹ̀gún gún wọn mọ́, láàrin gbogbo àwọn tí wọ́n yí wọn ká tí wọ́n sì ń kẹ́gàn wọn. Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA. “Nígbà tí mo bá kó àwọn ará ilé Israẹli jọ kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí mo fọ́n wọn ká sí, tí mo sì fi ìwà mímọ́ mi hàn láàrin wọn, lójú àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, wọn óo máa gbé ilẹ̀ tiwọn, ilẹ̀ tí mo fún Jakọbu iranṣẹ mi. Wọn óo máa gbé ibẹ̀ láìbẹ̀rù; wọn óo kọ́ ilé, wọn óo sì ṣe ọgbà àjàrà, wọn óo máa gbé láìbẹ̀rù nígbà tí mo bá ṣe ìdájọ́ gbogbo àwọn tí wọ́n yí wọn ká, tí wọ́n sì ti kẹ́gàn wọn. Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn.” Ní ọjọ́ kejila oṣù kẹwaa ọdún kẹwaa, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀; Ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú rẹ sí Farao ọba Ijipti, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa òun ati gbogbo àwọn ará Ijipti pé, OLUWA Ọlọrun ní: Wò ó, mo lòdì sí ọ, ìwọ Farao, ọba Ijipti, Ìwọ diragoni ńlá tí o wà láàrin odò rẹ; tí o wí pé, ‘Èmi ni mo ni odò Naili mi; ara mi ni mo dá a fún.’ N óo fi ìwọ̀ kọ́ ọ lẹ́nu, n óo sì jẹ́ kí àwọn ẹja inú odò Naili so mọ́ ìpẹ́ rẹ; n óo sì fà ọ́ jáde kúrò ninu odò Naili rẹ pẹlu gbogbo àwọn ẹja inú odò rẹ tí wọn óo so mọ́ ọ lára. N óo gbé ọ jù sinu aṣálẹ̀, ìwọ ati gbogbo ẹja inú odò Naili rẹ. Ẹ ó bọ́ lulẹ̀ ninu pápá tí ó tẹ́jú. Ẹnìkan kò sì ní kó òkú yín jọ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní sin yín. Mo ti fi yín ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹranko ati àwọn ẹyẹ. Gbogbo àwọn tí wọn ń gbé Ijipti yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA. “Nítorí pé ẹ fi ara yín ṣe ọ̀pá tí àwọn ọmọ Israẹli gbára lé; ṣugbọn ọ̀pá tí kò gbani dúró ni yín. Nígbà tí wọ́n gba yín mú, dídá ni ẹ dá mọ́ wọn lọ́wọ́, tí ẹ ya wọ́n léjìká pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Nígbà tí wọ́n gbára le yín, ẹ dá ẹ sì jẹ́ kí wọ́n dá lẹ́yìn.” Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní: “Wò ó, n óo fi ogun jà yín, n óo sì pa yín run, ati eniyan ati ẹranko. Ilẹ̀ Ijipti yóo di ahoro, yóo sì di aṣálẹ̀. Wọn yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA. “Nítorí o wí pé, ‘Èmi ni mo ni odò Naili, ara mi ni mo dá a fún,’ nítorí náà, mo lòdì sí ìwọ ati àwọn odò rẹ, n óo sì sọ ilẹ̀ Ijipti di ahoro ati aṣálẹ̀ patapata láti Migidoli dé Siene, títí dé ààlà Etiopia. Eniyan tabi ẹranko kò ní gba ibẹ̀ kọjá, ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀ fún ogoji ọdún. N óo sọ ilẹ̀ Ijipti di ahoro patapata, n óo jẹ́ kí àwọn ìlú rẹ̀ di ahoro fún ogoji ọdún. N óo fọ́n àwọn ará Ijipti káàkiri gbogbo ayé, n óo sì tú wọn ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.” OLUWA Ọlọrun ní, “Lẹ́yìn ogoji ọdún, n óo kó àwọn ará Ijipti jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè tí mo bá fọ́n wọn ká sí. N óo dá ire wọn pada, n óo kó wọn pada sí ilẹ̀ Patirosi, níbi tí a bí wọn sí. Wọn óo sì wà níbẹ̀ bí ìjọba tí kò lágbára. Òun ni yóo rẹlẹ̀ jù láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, kò ní lè gbé ara rẹ̀ ga láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn mọ́. N óo sọ wọ́n di kékeré tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní lè jọba lórí orílẹ̀-èdè kankan mọ́. Ijipti kò ní tó gbójú lé fún àwọn ọmọ Israẹli mọ́. Ijipti yóo máa rán wọn létí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, pé wọ́n ti wá bèèrè ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ àwọn ará Ijipti tẹ́lẹ̀ rí. Wọn óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun.” Ní ọjọ́ kinni, oṣù kinni, ọdún kẹtadinlọgbọn, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, Nebukadinesari ọba Babiloni mú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti ìlú Tire kíkankíkan. Wọ́n ru ẹrù títí orí gbogbo wọn pá, èjìká gbogbo wọn sì di egbò. Sibẹ òun ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kò rí èrè kankan gbà ninu gbogbo wahala tí wọ́n ṣe ní Tire. Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun óo fi ilẹ̀ Ijipti lé Nebukadinesari, ọba Babiloni lọ́wọ́. Yóo kó àwọn eniyan rẹ̀ lọ, yóo sì fi ọrọ̀ ilẹ̀ Ijipti ṣe ìkógun, èyí ni yóo jẹ́ èrè fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Mo ti fún un ní ilẹ̀ Ijipti gẹ́gẹ́ bí èrè gbogbo wahala rẹ̀, nítorí pé èmi ni ó ṣiṣẹ́ fún. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “Ní ọjọ́ náà, n óo gbé alágbára kan dìde ní Israẹli, n óo mú kí ìwọ Isikiẹli ó sọ̀rọ̀ láàrin wọn. Nígbà náà, wọn yóo mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ kí o sì wí pé, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn nítorí ọjọ́ burúkú tí ń bọ̀, nítorí ọjọ́ náà súnmọ́lé, ọjọ́ OLUWA ti dé tán, yóo jẹ́ ọjọ́ ìṣúdudu ati ìparun fún àwọn orílẹ̀-èdè. Ogun yóo jà ní Ijipti, ìrora yóo sì bá Etiopia. Nígbà tí ọpọlọpọ òkú bá sùn ní Ijipti, tí a kó ọrọ̀ rẹ̀ lọ, tí a sì wó ìpìlẹ̀ rẹ̀ lulẹ̀. “ ‘Àwọn ará Etiopia, ati Puti, ati Ludi, ati gbogbo ilẹ̀ Arabia ati Libia, ati gbogbo àwọn eniyan wa tí wọ́n jọ gbìmọ̀ pọ̀, ni ogun yóo pa.’ ” OLUWA ní, “Àwọn tí ń ran Ijipti lọ́wọ́ yóo ṣubú, ìgbéraga rẹ̀ yóo sì wálẹ̀; láti Migidoli títí dé Siene, wọn ó kú ikú ogun láàrin ìlú. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “Ijipti óo di ahoro patapata àwọn ìlú rẹ̀ yóo wà lára àwọn ìlú tí yóo tú patapata. Wọn yóo mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá dáná sun Ijipti, tí gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ bá ṣubú. “Nígbà tó bá tó àkókò, n óo rán àwọn ikọ̀ ninu ọkọ̀ ojú omi, wọn ó lọ dẹ́rù ba àwọn ará Etiopia tí wọn ń gbé láìfura. Wahala yóo dé bá àwọn ará Etiopia ní ọjọ́ ìparun Ijipti. Wò ó, ìparun náà ti dé tán.” OLUWA Ọlọrun ní, “N óo ti ọwọ́ Nebukadinesari, ọba Babiloni, fi òpin sí ọrọ̀ Ijipti. Òun ati àwọn eniyan rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè oníjàgídíjàgan jùlọ ni, yóo wá pa ilẹ̀ Ijipti run, wọn yóo yọ idà ti Ijipti, ọpọlọpọ yóo sì kú ní ilẹ̀ náà. N óo mú kí odò Naili gbẹ, n óo ta ilẹ̀ náà fún àwọn eniyan burúkú; n óo sì jẹ́ kí àwọn àjèjì sọ ilẹ̀ náà ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ di ahoro. Èmi OLUWA ní mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA Ọlọrun ní, “N óo fọ́ àwọn ère tí ó wà ní Memfisi, n óo sì pa wọ́n run. Kò ní sí ọba ní ilẹ̀ Ijipti mọ́, n óo jẹ́ kí ìbẹ̀rù dé bá ilẹ̀ Ijipti. N óo sọ Patirosi di ahoro, n óo sì dáná sun Soani, n óo sì ṣe ìdájọ́ fún ìlú Tebesi. N óo bínú sí Pelusiumu, ibi ààbò Ijipti, n óo sì pa ogunlọ́gọ̀ àwọn tí ń gbé Tebesi. N óo dáná sun Ijipti, Pelusiumu yóo sì wà ninu ìrora ńlá. N óo fi idà pa àwọn ọdọmọkunrin Oni ati ti Pibeseti; a óo sì kó àwọn obinrin wọn lọ sí ìgbèkùn. Ojú ọjọ́ yóo ṣókùnkùn ní Tehafinehesi nígbà tí mo bá ṣẹ́ ọ̀pá ìjọba Ijipti, agbára tí ó ń gbéraga sí yóo sì dópin. Ìkùukùu óo bò ó mọ́lẹ̀; wọn óo sì kó àwọn ọmọbinrin rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe ṣe ìdájọ́ Ijipti, wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” Ní ọjọ́ keje, oṣù kinni ọdún kọkanla, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, mo ti ṣẹ́ Farao, ọba Ijipti, lápá, a kò sì tíì dí i, kí ọgbẹ́ rẹ̀ fi san, kí ó sì fi lágbára láti gbá idà mú. Nítorí náà, mo lòdì sí Farao, ọba Ijipti. Èmi OLUWA Ọlọrun ní mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo ṣẹ́ ẹ ní apá mejeeji: ati èyí tó ṣì lágbára, ati èyí tí ó ti ṣẹ́ tẹ́lẹ̀; n óo sì gbọn idà bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀. N óo fọ́n àwọn ará Ijipti ká orílẹ̀-èdè ayé, n óo sì tú wọn káàkiri gbogbo ilẹ̀ ayé. N óo fún ọba Babiloni lágbára, n óo sì fi idà mi lé e lọ́wọ́; ṣugbọn n óo ṣẹ́ Farao lápá; yóo máa kérora níwájú rẹ̀ bí ẹni tí a ṣá lọ́gbẹ́ tí ó ń kú lọ. N óo fún ọba Babiloni lágbára, ṣugbọn ọwọ́ Farao yóo rọ. Wọn yóo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA. Nígbà tí mo bá fi idà mi lé ọba Babiloni lọ́wọ́, yóo fa idà náà yọ yóo gbógun ti ilẹ̀ Ijipti. N óo fọ́n àwọn ará Ijipti ká sáàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, n óo sì tú wọn káàkiri gbogbo ilẹ̀ ayé. Wọn óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” Ní ọjọ́ kinni, oṣù kẹta, ọdún kọkanla tí a ti wà ní ìgbèkùn, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún Farao, ọba Ijipti, pẹlu ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ pé, Ta ni ó lágbára tó ọ? Wò ó! Mo fi ọ́ wé igi kedari Lẹbanoni, àwọn ẹ̀ka rẹ̀ lẹ́wà, wọ́n sì ní ìbòòji ó ga fíofío, orí rẹ̀ sì kan ìkùukùu lójú ọ̀run. Omi mú kí ó dàgbà, ibú omi sì mú kí ó ga. Ó ń mú kí àwọn odò rẹ̀ ṣàn yí ibi tí a gbìn ín sí ká. Ó ń mú kí odò rẹ̀ ṣàn lọ síbi gbogbo igi igbó. Nítorí náà, ó ga sókè fíofío, ju gbogbo igi inú igbó lọ. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tóbi, wọ́n sì gùn, nítorí ọpọlọpọ omi tí ó ń rí. Gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run, pa ìtẹ́ sára àwọn ẹ̀ka rẹ̀. Lábẹ́ rẹ̀ ni gbogbo ẹranko inú igbó ń bímọ sí. Gbogbo orílẹ̀-èdè ńláńlá sì fi ìbòòji abẹ́ rẹ̀ ṣe ibùgbé. Ó tóbi, ó lọ́lá ẹ̀ka rẹ̀ sì lẹ́wà nítorí pé gbòǹgbò rẹ̀ wọ ilẹ̀ lọ, ó sì kan ọpọlọpọ omi nísàlẹ̀ ilẹ̀. Igi kedari tí ó wà ninu ọgbà Ọlọrun kò lè farawé e. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀ka igi firi kò sì tó ẹ̀ka rẹ̀. Ẹ̀ka igi kankan kò dàbí ẹ̀ka rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí igikígi ninu ọgbà Ọlọrun tí ó lẹ́wà bíi rẹ̀. Mo dá a ní arẹwà, pẹlu ẹ̀ka tí ó pọ̀. Gbogbo igi ọgbà Edẹni, tí ó wà ninu ọgbà Ọlọrun sì ń jowú rẹ̀. “Nítorí pé ó ga sókè fíofío, góńgó orí rẹ̀ wọ inú ìkùukùu lójú ọ̀run, ọkàn rẹ̀ sì kún fún ìgbéraga nítorí gíga rẹ̀. N óo fi lé ẹni tí ó lágbára jù láàrin àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́, yóo sì ṣe é fún un gẹ́gẹ́ bí ìwà ìkà rẹ̀. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo lé e jáde. Àwọn àjèjì láti inú orílẹ̀-èdè, tí ó burú jùlọ, yóo gé e lulẹ̀, wọn yóo sì fi í sílẹ̀. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóo bọ́ sílẹ̀ lórí àwọn òkè ati ní àwọn àfonífojì, igi rẹ̀ yóo sì wà nílẹ̀ káàkiri ní gbogbo ipadò ilẹ̀ náà. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo kúrò lábẹ́ òjìji rẹ̀, wọn yóo sì fi sílẹ̀. Gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run yóo kọ́lé sórí ìtì igi rẹ̀ tí ó wó lulẹ̀. Gbogbo ẹranko inú igbó yóo tẹ àwọn ẹ̀ka rẹ̀ mọ́lẹ̀. Gbogbo èyí yóo ṣẹlẹ̀ kí igi mìíràn tí ó bá wà lẹ́bàá omi náà má baà ga fíofío mọ́, tabi kí orí rẹ̀ wọ inú ìkùukùu ní ojú ọ̀run. Kò sì ní sí igi tí ń fa omi, tí yóo ga tó ọ; nítorí gbogbo wọn ni wọn óo kú, tí wọn óo sì lọ sí ìsàlẹ̀ ọ̀gbun ilẹ̀ bí àwọn alààyè eniyan tí wọ́n ti lọ sí ipò òkú.” OLUWA Ọlọrun ní: “Nígbà tí ó bá wọ isà òkú ọ̀gbun ilẹ̀ pàápàá, n óo ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, n óo sé àwọn odò n óo sì ti orísun omi ìsàlẹ̀ ilẹ̀ nítorí rẹ̀, òkùnkùn óo bo Lẹbanoni, gbogbo igi inú igbó yóo gbẹ nítorí rẹ̀. Ìró wíwó rẹ̀ yóo mi àwọn orílẹ̀-èdè tìtì. Nígbà tí mo bá wó o lulẹ̀ tí mo bá sọ ọ́ sinu isà òkú pẹlu àwọn tí wọ́n ti lọ sí ipò òkú; gbogbo àwọn igi Edẹni, ati àwọn igi tí wọ́n dára jù ní Lẹbanoni, gbogbo àwọn igi tí ń rí omi mu lábẹ́ ilẹ̀ ni ara yóo tù. Àwọn náà yóo lọ sí ipò òkú pẹlu rẹ̀, sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n fi idà pa; àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ń gbé abẹ́ òjìji rẹ̀ yóo sì parun. “Ògo ati títóbi ta ni a lè fi wé tìrẹ láàrin àwọn igi tí ó wà ní Edẹni? Ṣugbọn a óo gé ọ lulẹ̀ pẹlu àwọn igi ọgbà Edẹni, a óo sì wọ́ ọ sọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀. O óo wà nílẹ̀ láàrin àwọn aláìkọlà, pẹlu àwọn tí a fi idà pa. Farao ati ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ ni mò ń sọ nípa wọn. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” Ní ọjọ́ kinni oṣù kejila, ọdún kejila tí a ti wà ní ìgbèkùn, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀. Ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, gbé ohùn sókè kí o kọ orin arò nípa Farao, ọba Ijipti. Wí fún un pé ó ka ara rẹ̀ kún kinniun láàrin àwọn orílẹ̀-èdè. Ṣugbọn ó dàbí diragoni ninu omi. Ó ń jáde tagbára tagbára láti inú odò, ó ń fẹsẹ̀ da omi rú, ó sì ń dọ̀tí àwọn odò. Sọ pé èmi, OLUWA Ọlọrun ní n óo da àwọ̀n mi bò ó níṣojú ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan; wọn óo sì fi àwọ̀n mi wọ́ ọ sókè. N óo wọ́ ọ jù sórí ilẹ̀; inú pápá ni n óo sọ ọ́ sí, n óo jẹ́ kí gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run pa ìtẹ́ wọn lé e lórí. N óo sì jẹ́ kí àwọn ẹranko ilẹ̀ ayé jẹ ẹran ara rẹ. N óo sọ ẹran ara rẹ̀ káàkiri sí orí àwọn òkè. N óo sì fi òkú rẹ̀ kún àwọn àfonífojì. N óo tú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dà sórí ilẹ̀ ati sórí àwọn òkè, gbogbo ipadò yóo sì kún fún ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Nígbà tí mo bá pa á rẹ́, n óo bo ojú ọ̀run; n óo jẹ́ kí ìràwọ̀ ṣóòkùn n óo fi ìkùukùu bo oòrùn lójú, òṣùpá kò sì ní tan ìmọ́lẹ̀. Gbogbo àwọn ìmọ́lẹ̀ tí ó ń tàn lójú ọ̀run ni n óo jẹ́ kí ó di òkùnkùn lórí rẹ̀, n óo jẹ́ kí òkùnkùn bo ilẹ̀ rẹ̀. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “N óo jẹ́ kí ọkàn ọpọlọpọ eniyan dààmú nígbà tí mo bá ko yín ní ìgbèkùn lọ sí ilẹ̀ tí ẹ kò dé rí, láàrin àwọn orílẹ̀-èdè ayé. N óo jẹ́ kí ẹnu ya ọpọlọpọ eniyan nítorí yín, àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì wárìrì nítorí tiyín, nígbà tí mo bá ń fi idà mi lójú wọn, olukuluku wọn óo máa wárìrì nígbàkúùgbà nítorí ẹ̀mí ara rẹ̀, ní ọjọ́ ìṣubú rẹ.” OLUWA Ọlọrun sọ fún ọba Ijipti pé, “Ọba Babiloni yóo fi idà pa yín. N óo wá àwọn alágbára, àwọn tí wọ́n burú jùlọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, n óo jẹ́ kí gbogbo wọn fi idà pa ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ. Wọn yóo sọ ìgbéraga Ijipti di asán, ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ yóo sì parun. N óo pa gbogbo ẹran ọ̀sìn Ijipti tí ó wà ní etí odò run. Àwọn eniyan kò sì ní fi ẹsẹ̀ da omi rú mọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹranko kò ní fi pátákò da odò rú mọ́. N óo wá jẹ́ kí odò wọn ó tòrò, kí wọn máa ṣàn bí òróró. Èmi OLUWA Ọlọrun, ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Nígbà tí mo bá sọ ilẹ̀ Ijipti di ahoro, tí mo bá pa gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ run; tí mo bá pa gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ run, wọn yóo mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA. Àwọn eniyan yóo máa kọ ọ̀rọ̀ yìí ní orin arò; àwọn ọmọbinrin ní àwọn orílẹ̀-èdè ni yóo máa kọ ọ́. Wọn óo máa kọ ọ́ nípa Ijipti ati ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀. Èmi, OLUWA Ọlọrun, ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” Ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù kinni, ọdún kejila tí a ti wà ní ìgbèkùn, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn lórí ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan Ijipti, rán àwọn ati àwọn orílẹ̀-èdè ọlọ́lá yòókù lọ sinu isà òkú, sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n ti fi ilẹ̀ bora. Sọ fún wọn pé, ‘Ta ni ó lẹ́wà jùlọ? Sùn kalẹ̀, kí á sì tẹ́ ọ sọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà.’ “Wọn yóo ṣubú láàrin àwọn tí wọ́n kú ikú ogun; ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ yóo ṣubú pẹlu rẹ̀. Àwọn olórí tí wọ́n jẹ́ akọni ati àwọn olùrànlọ́wọ́ wọn yóo máa sọ nípa wọn ninu isà òkú pé, ‘Àwọn aláìkọlà tí a fi idà pa ti ṣubú, wọ́n ti wọlẹ̀, wọ́n sùn, wọn kò lè mira.’ “Asiria náà wà níbẹ̀, pẹlu gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ibojì àwọn tí wọ́n ti kú yí i ká. Gbogbo wọn ni wọ́n ti kú ikú ogun. Ibojì rẹ̀ wà ní ìpẹ̀kun isà òkú. Ibojì àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì tò yí tirẹ̀ ká. Àwọn tí ń dẹ́rù bani nígbà tí wọ́n wà láyé, gbogbo wọn ni wọ́n ti kú ikú ogun. “Elamu náà wà níbẹ̀, pẹlu gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ibojì wọn yí ibojì rẹ̀ ká. Gbogbo wọn ni wọ́n ti kú ikú ogun. Wọ́n sì lọ sinu isà òkú ní àìkọlà abẹ́. Àwọn tí ń dẹ́rù bani nígbà tí wọ́n wà láàyè, wọ́n fi ìtìjú wọlẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀, wọn lọ bá àwọn tí wọ́n wà ní ipò òkú. Wọ́n tẹ́ ibùsùn fún Elamu láàrin àwọn tí wọ́n kú sójú ogun pẹlu ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀. Ibojì wọn yí tirẹ̀ ká, gbogbo wọn ni a fi idà pa láìkọlà abẹ́. Wọ́n ń dẹ́rù ba àwọn eniyan nígbà tí wọ́n wà láàyè. Wọ́n fi ìtìjú wọlẹ̀ lọ, wọ́n lọ bá àwọn tí wọ́n wà ní ipò òkú. A kó gbogbo wọn pọ̀ mọ́ àwọn tí wọ́n kú sójú ogun. “Meṣeki ati Tubali wà níbẹ̀ pẹlu ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan wọn. Ibojì wọn yí ibojì rẹ̀ ká, gbogbo wọn ni wọ́n kú lójú ogun ní aláìkọlà. Nítorí wọ́n ń dẹ́rù bani nígbà tí wọ́n wà láàyè. Wọn kò sin wọ́n bí àwọn alágbára tí wọ́n wà ní àtijọ́ tí wọ́n sin sí ibojì pẹlu ohun ìjà ogun wọn lára wọn: àwọn tí a gbé orí wọn lé idà wọn, wọ́n sì fi asà wọn bo egungun wọn mọ́lẹ̀; nítorí àwọn alágbára wọnyi dẹ́rù bani nígbà tí wọ́n wà láàyè. “Nítorí náà, a óo wó ọ mọ́lẹ̀, o óo sì sùn láàrin àwọn aláìkọlà pẹlu àwọn tí wọ́n kú lójú ogun. “Edomu náà wà níbẹ̀ pẹlu àwọn ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀. Bí wọ́n ti lágbára tó, wọ́n sùn pẹlu àwọn tí wọ́n kú lójú ogun. Wọ́n sùn pẹlu àwọn aláìkọlà, pẹlu àwọn tí wọ́n ti lọ sí ipò òkú. “Gbogbo àwọn olórí láti apá àríwá wà níbẹ̀, ati gbogbo àwọn ará Sidoni, tí wọ́n fi ìtìjú wọlé lọ sí ipò òkú pẹlu àwọn tí wọ́n kú lójú ogun. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lo agbára wọn láti dẹ́rù bani, wọ́n sùn láìkọlà, pẹlu ìtìjú, pẹlu àwọn tí wọ́n kú lójú ogun. Pẹlu àwọn tí wọ́n lọ sinu isà òkú. “Nígbà tí Farao bá rí wọn, Tòun ti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí a fi idà pa, yóo dá ara rẹ̀ lọ́kàn le, nítorí gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. “Mo mú kí Farao dẹ́rù ba àwọn eniyan nígbà tí ó wà láyé. Nítorí náà, a óo sin òun ati ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ sí ààrin àwọn aláìkọlà, láàrin àwọn tí wọ́n kú lójú ogun.” Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA Ọlọrun wí. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, bá àwọn eniyan rẹ sọ̀rọ̀. Wí fún wọn pé bí mo bá jẹ́ kí ogun jà ní ilẹ̀ kan, tí àwọn eniyan ibẹ̀ bá yan ọ̀kan ninu wọn, tí wọ́n fi ṣe olùṣọ́; bí ó bá rí ogun tí ń bọ̀ wá sí ilẹ̀ náà, tí ó bá fọn fèrè tí ó fi kìlọ̀ fún àwọn eniyan, bí ẹnìkan bá gbọ́ ìró fèrè náà, ṣugbọn tí kò bá bìkítà fún ogun àgbọ́-tẹ́lẹ̀ yìí, bí ogun bá pa á orí ara rẹ̀ ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà. Ó gbọ́ ìró fèrè ṣugbọn kò bìkítà, nítorí náà orí ara rẹ̀ ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà. Bí ó bá gbọ́ ìkìlọ̀ ni, kì bá gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là. Ṣugbọn bí olùṣọ́ bá rí i pé ogun ń bọ̀, tí kò bá fọn fèrè kí ó kìlọ̀ fún àwọn eniyan; bí ogun bá pa ẹnikẹ́ni ninu wọn, ẹni tí ogun pa yóo kú ninu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn èmi OLUWA óo bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ olùṣọ́ náà. “Ọmọ eniyan, ìwọ ni mo yàn ní olùṣọ́ fún ilé Israẹli; nígbàkúùgbà tí o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́nu mi, o níláti bá mi kìlọ̀ fún wọn. Bí mo bá wí fún eniyan burúkú pé yóo kú, tí o kò sì kìlọ̀ fún un pé kí ó yipada kúrò ní ọ̀nà ibi rẹ̀, eniyan burúkú náà yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn ọwọ́ rẹ ni n óo ti bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Ṣugbọn bí ìwọ bá kìlọ̀ fún eniyan burúkú pé kí ó yipada kúrò ní ọ̀nà ibi rẹ̀, tí kò sì yipada, yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn ìwọ ti gba ẹ̀mí ara tìrẹ là. “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé mo gbọ́ ohun tí wọn ń sọ pé, ‘Àìdára wa ati ẹ̀ṣẹ̀ wa wà lórí wa, a sì ń joró nítorí wọn; báwo ni a óo ṣe yè?’ Wí fún wọn pé èmi OLUWA ní, mo fi ara mi búra pé inú mi kò dùn sí ikú eniyan burúkú, ohun tí mo fẹ́ ni pé kí ó yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ó sì yè. Ẹ yipada! Ẹ yipada kúrò ninu iṣẹ́ ibi yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, kí ló dé tí ẹ fi fẹ́ kú? “Ìwọ ọmọ eniyan, wí fún àwọn eniyan rẹ pé, bí olódodo bá dẹ́ṣẹ̀ ìwà òdodo rẹ̀ kò ní gbà á là, bẹ́ẹ̀ sì ni bí eniyan burúkú bá yí ìwà rẹ̀ pada, kò ní kú nítorí ìwà burúkú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni bí olódodo bá dẹ́ṣẹ̀, kò ní yè nítorí òdodo rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo wí fún olódodo pé yóo yè, bí ó bá gbójú lé òdodo ara rẹ̀, tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, n kò ní ranti ọ̀kankan ninu ìwà òdodo rẹ̀, yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá. Bí mo bá sì wí fún eniyan burúkú pé dandan ni pé kí ó kú, bí ó bá yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó dára, tí ó sì tọ́, bí ó bá dá nǹkan tí ẹni tí ó jẹ ẹ́ ní gbèsè fi ṣe ìdúró pada, tí ó sì dá gbogbo nǹkan tí ó jí pada, tí ó ń rìn ní ọ̀nà ìyè láì dẹ́ṣẹ̀, dájúdájú yóo yè; kò ní kú. N kò ní ranti gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí o ti dá mọ́. Nítorí pé ó ti ṣe ohun tí ó dára, tí ó sì tọ́, yóo yè. “Sibẹsibẹ, àwọn eniyan rẹ ń wí pé, ‘Ọ̀nà OLUWA kò tọ́,’ bẹ́ẹ̀ sì ni ọ̀nà tiwọn gan-an ni kò tọ́. Bí olódodo bá yipada kúrò ninu ìwà òdodo rẹ̀, tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Bí eniyan burúkú bá sì yipada kúrò ninu ibi tí ó ń ṣe, tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó dára tí ó sì tọ́, yóo yè nítorí rere tí ó ṣe. Sibẹsibẹ, ẹ̀ ń wí pé, ‘ọ̀nà OLUWA kò tọ́.’ Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ìwà olukuluku yín ni n óo fi dá a lẹ́jọ́.” Ní ọjọ́ karun-un oṣù kẹwaa ọdún kejila tí a ti wà ní ìgbèkùn, ẹnìkan tí ó sá àsálà kúrò ní Jerusalẹmu wá sọ́dọ̀ mi, ó ní, “Ogun ti kó Jerusalẹmu.” Ẹ̀mí OLUWA ti bà lé mi ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tí ó ṣáájú ọjọ́ tí ẹni tí ó sá àsálà náà dé, OLUWA sì ti là mí lóhùn kí ọkunrin náà tó dé ọ̀dọ̀ mi ní àárọ̀ ọjọ́ keji; n kò sì yadi mọ́. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ Israẹli tí ó ti di aṣálẹ̀ wọnyi, ń wí pé, ‘Ẹnìkan péré ni Abrahamu, bẹ́ẹ̀ ó sì gba ilẹ̀ yìí. Àwa pọ̀ ní tiwa, nítorí náà, a ti fi ilẹ̀ yìí fún wa, kí á gbà á ló kù.’ “Nítorí náà, wí fún wọn pé OLUWA Ọlọrun ní, Ẹ̀ ń jẹ ẹran pẹlu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ̀ ń bọ oriṣa, ẹ sì ń pa eniyan, ṣé ẹ rò pé ilẹ̀ náà yóo di tiyín? Idà ni ó kù tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé; ẹ̀ ń ṣe ohun ìríra, ẹ̀ ń bá iyawo ara yín lòpọ̀, ẹ sì rò pé ẹ óo jogún ilẹ̀ yìí? “Mo fi ara mi búra, ogun ni yóo pa àwọn tí ń gbé àwọn ìlú tí ó ti di ahoro. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo jẹ́ kí ẹranko burúkú pa àwọn tí wọ́n wà ninu pápá jẹ, àjàkálẹ̀ àrùn yóo sì pa àwọn tí wọ́n sápamọ́ sí ibi ààbò ati ninu ihò àpáta. N óo sọ ilẹ̀ yìí di ahoro ati aṣálẹ̀. Agbára tí ó ń gbéraga sí yóo dópin. Àwọn òkè Israẹli yóo di ahoro tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ní gba ibẹ̀ kọjá. Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá sọ ilẹ̀ náà di ahoro ati aṣálẹ̀, nítorí gbogbo ìwà ìríra tí wọ́n ti hù. “Ní tìrẹ, ìwọ ọmọ eniyan, àwọn eniyan rẹ tí ń sọ̀rọ̀ rẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri ati lẹ́nu ọ̀nà àbáwọlé wọn, wọ́n ń wí fún ara wọn pé: ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ gbọ́ ohun tí OLUWA wí.’ Wọ́n ń wá sọ́dọ̀ rẹ bí àwọn eniyan tií wá, wọ́n sì ń jókòó níwájú rẹ bí eniyan mi. Wọ́n ń gbọ́ ohun tí ò ń wí, ṣugbọn wọn kò ní ṣe é; nítorí pé ẹnu lásán ni wọ́n fi ń sọ pé wọ́n ní ìfẹ́ pupọ, ṣugbọn níbi èrè tí wọn ó jẹ ni ọkàn wọn wà. Lójú wọn, o dàbí olóhùn iyọ̀ tí ń kọrin ìfẹ́, tí ó sì mọ ohun èlò orin lò dáradára. Wọ́n ń gbọ́ ohun tí ò ń wí, ṣugbọn wọn kò ní ṣe é. Ṣugbọn nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ, (bẹ́ẹ̀ yóo sì ṣẹ), wọn óo wá mọ̀ pé wolii kan wà láàrin wọn.” OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ kí o fi bá àwọn olùṣọ́-aguntan Israẹli wí, fi àsọtẹ́lẹ̀ bá àwọn olórí Israẹli wí pé, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Háà, ẹ̀yin olórí Israẹli tí ẹ̀ ń wá oúnjẹ fún ara yín, ṣé kò yẹ kí olùṣọ́-aguntan máa pèsè oúnjẹ fún àwọn aguntan rẹ̀? Ẹ̀yin ń jẹ ẹran ọlọ́ràá, ẹ̀ ń fi irun aguntan bo ara yín, ẹ̀ ń pa aguntan tí ó sanra jẹ; ṣugbọn ẹ kò fún àwọn aguntan ní oúnjẹ. Ẹ kò tọ́jú àwọn tí wọn kò lágbára, ẹ kò tọ́jú àwọn tí ń ṣàìsàn, ẹ kò tọ́jú ẹsẹ̀ àwọn tí wọn dá lẹ́sẹ̀, ẹ kò mú àwọn tí wọn ń ṣáko lọ pada wálé; ẹ kò sì wá àwọn tí wọ́n sọnù. Pẹlu ipá ati ọwọ́-líle ni ẹ fi ń ṣe àkóso wọn. Nítorí náà, wọ́n túká nítorí pé wọn kò ní olùṣọ́, wọ́n sì di ìjẹ fún àwọn ẹranko burúkú. Àwọn aguntan mi túká, wọ́n ń káàkiri lórí gbogbo òkè ńlá ati gbogbo òkè kéékèèké. Àwọn aguntan mi fọ́n káàkiri sórí gbogbo ilẹ̀ ayé. Kò sí ẹni tí ó bèèrè wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó wá wọn.’ “Nítorí náà, ẹ̀yin, olùṣọ́-aguntan, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí. OLUWA Ọlọrun fi ara rẹ̀ búra ó ní, ‘Àwọn aguntan mi di ìjẹ, fún gbogbo ẹranko nítorí pé wọn kò ní olùṣọ́; nítorí pé àwọn tí ń ṣọ́ wọn kò wá wọn, kàkà bẹ́ẹ̀ oúnjẹ ni wọ́n ń wá sẹ́nu ara wọn, wọn kò bọ́ àwọn aguntan mi.’ Nítorí náà, ẹ gbọ́, ẹ̀yin olùṣọ́-aguntan: ‘Mo lòdì sí ẹ̀yin olùṣọ́-aguntan, n óo sì bèèrè àwọn aguntan mi lọ́wọ́ yín. N óo da yín dúró lẹ́nu iṣẹ́ olùṣọ́-aguntan, ẹ kò sì ní rí ààyè bọ́ ara yín mọ́. N óo gba àwọn aguntan mi lẹ́nu yín, ẹ kò sì ní rí wọn pa jẹ mọ́.’ ” OLUWA Ọlọrun ní, “Ẹ wò ó! Èmi fúnra mi ni n óo wá àwọn aguntan mi, àwárí ni n óo sì wá wọn. Bí olùṣọ́-aguntan tií wá àwọn aguntan rẹ̀ tí ó bá jẹ lọ, bẹ́ẹ̀ ni n óo wá àwọn aguntan mi, n óo sì yọ wọ́n kúrò ninu gbogbo ibi tí wọ́n fọ́nká sí ní ọjọ́ tí ìkùukùu bo ilẹ̀, tí òkùnkùn sì ṣú. N óo mú wọn jáde kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, n óo kó wọn jọ láti gbogbo ilẹ̀ ayé, n óo sì kó wọn wá sí ilẹ̀ tiwọn. N óo máa bọ́ wọn lórí àwọn òkè Israẹli, lẹ́bàá orísun omi ati gbogbo ibi tí àwọn eniyan ń gbé ní Israẹli. N óo fún wọn ní koríko tí ó dára jẹ, orí òkè Israẹli sì ni wọn óo ti máa jẹ koríko. Níbẹ̀, ninu pápá oko tí ó dára ni wọn óo dùbúlẹ̀ sí; ninu pápá oko tútù, wọn yóo sì máa jẹ lórí àwọn òkè Israẹli. Èmi fúnra mi ni n óo jẹ́ olùṣọ́ àwọn aguntan mi, n óo sì mú wọn dùbúlẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA Ọlọrun sọ. “N óo wá àwọn tí ó sọnù, n óo sì mú àwọn tí wọ́n ṣáko lọ pada, n óo tọ́jú ọgbẹ́ àwọn tí wọ́n farapa, n óo fún àwọn tí kò lókun lágbára, ṣugbọn àwọn tí wọ́n sanra ati àwọn tí wọ́n lágbára ni n óo parun, nítorí òtítọ́ inú ni n óo fi ṣọ́ àwọn aguntan mi. “Ní tiyín, ẹ̀yin agbo ẹran mi, èmi OLUWA Ọlọrun ni n óo ṣe ìdájọ́ láàrin aguntan kan ati aguntan keji, ati láàrin àgbò ati òbúkọ. Ṣé kí ẹ máa jẹ oko ninu pápá dáradára kò to yín ni ẹ ṣe ń fi ẹsẹ̀ tẹ àjẹkù yín mọ́lẹ̀? Ṣé kí ẹ mu ninu omi tí ó tòrò kò to yín ni ẹ ṣe fẹsẹ̀ da omi yòókù rú? Ṣé àjẹkù tí ẹ ti fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀ ni ó yẹ kí àwọn aguntan tèmi máa jẹ; omi àmukù tí ẹ ti fi ẹsẹ̀ dàrú sì ni ó yẹ kí wọn máa mu? “Nítorí náà, ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun, ń sọ fun yín ni pé: mo ṣetán tí n óo ṣe ìdájọ́ fún àwọn aguntan tí ó sanra ati àwọn aguntan tí kò lókun ninu. Nítorí pé ẹ̀ ń fi ẹ̀gbẹ́ ti àwọn tí wọn kò lágbára sọnù, ẹ sì ń kàn wọ́n níwo títí tí ẹ fi tú wọn ká. N óo gba àwọn aguntan mi sílẹ̀, wọn kò ní jẹ́ ìjẹ mọ́, n óo sì ṣe ìdájọ́ láàrin aguntan kan ati aguntan keji. Olùṣọ́ kanṣoṣo ni n óo yàn fún wọn, òun náà sì ni Dafidi, iranṣẹ mi. Yóo máa bọ́ wọn, yóo sì máa ṣe olùṣọ́ wọn. Èmi OLUWA ni n óo jẹ́ Ọlọrun wọn; Dafidi, iranṣẹ mi ni yóo sì jẹ́ ọba láàrin wọn, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo bá wọn dá majẹmu alaafia; n óo lé àwọn ẹranko burúkú kúrò ní ilẹ̀ náà, wọn yóo máa gbé inú aṣálẹ̀ ati inú igbó láìléwu. “N óo bukun àwọn, ati gbogbo agbègbè òkè mi. N óo máa jẹ́ kí òjò máa rọ̀ lásìkò wọn, òjò ibukun ni yóo sì máa jẹ́. Igi inú oko yóo máa so; ilẹ̀ yóo sì máa mú ọpọlọpọ irúgbìn jáde. Àwọn eniyan óo máa gbé ilẹ̀ wọn láìléwu, wọn óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá ṣẹ́ ọ̀pá àjàgà wọn, tí mo bá sì gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn tí ó kó wọn lẹ́rú. Wọn kò ní jẹ́ ìjẹ fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn mọ́; bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹranko ilẹ̀ yìí kò ní pa wọ́n jẹ mọ́. Wọn óo máa gbé ilẹ̀ wọn láìléwu, ẹnìkan kan kò sì ní dẹ́rù bà wọ́n mọ́. N óo fún wọn ní ọpọlọpọ nǹkan kórè ninu ohun tí wọ́n bá gbìn, ìyàn kò ní run wọ́n mọ́ ní ilẹ̀ náà, àwọn orílẹ̀-èdè yòókù kò sì ní fi wọ́n ṣẹ̀sín mọ́. Wọn óo mọ̀ pé èmi, OLUWA Ọlọrun wọn, wà pẹlu wọn, ati pé àwọn ọmọ Israẹli sì ni eniyan mi. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “Ẹ̀yin aguntan mi, aguntan pápá mi, ẹ̀yin ni eniyan mi; èmi sì ni Ọlọrun yín.” OLUWA Ọlọrun ló sọ bẹ́ẹ̀. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, dojú kọ òkè Seiri, kí o sì fi àsọtẹ́lẹ̀ bá a wí. Wí fún un pé OLUWA Ọlọrun ní, ‘Wò ó! Mo lòdì sí ọ, ìwọ Òkè Seiri. N óo nawọ́ ibinu sí ọ, n óo sọ ọ́ di ahoro ati aṣálẹ̀. N óo sọ àwọn ìlú rẹ di aṣálẹ̀ ìwọ pàápàá yóo sì di ahoro; o óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA. “ ‘Nítorí pé ò ń fẹ́ràn ati máa ṣe ọ̀tá lọ títí, o sì fa àwọn ọmọ Israẹli fún ogun pa nígbà tí ìṣòro dé bá wọn, tí wọn ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, mo fi ara mi búra pé, n óo fi ọ́ fún ikú pa, ikú yóo máa lépa rẹ, nítorí pé apànìyàn ni ọ́; ikú yóo máa lépa ìwọ náà. N óo sọ òkè Seiri di aṣálẹ̀ ati ahoro. N óo pa gbogbo àwọn tí ń lọ tí ń bọ̀ níbẹ̀. N óo da òkú sí orí àwọn òkè ńláńlá rẹ, yóo kún. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn òkè kéékèèké rẹ, ati gbogbo àwọn àfonífojì rẹ, ati gbogbo ipa odò rẹ. Òkú àwọn tí a fi idà pa ni yóo kúnbẹ̀. N óo sọ ọ́ di ahoro títí lae, ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé inú àwọn ìlú rẹ mọ́. O óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA. “ ‘Nítorí ẹ̀yin ará Edomu sọ pé, àwọn orílẹ̀-èdè mejeeji wọnyi ati ilẹ̀ wọn yóo di tiyín ati pé ẹ óo jogún rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA wà níbẹ̀. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, mo fi ara mi búra, bí ẹ ti fi ìrúnú ati owú ṣe sí wọn nítorí pé ẹ kórìíra wọn, bẹ́ẹ̀ gan-an ni èmi náà óo ṣe sí ọ; n óo sì jẹ́ kí ẹ mọ irú ẹni tí mo jẹ́ nígbà tí mo bá dájọ́ fun yín. Ẹ óo mọ̀ pé èmi OLUWA gbọ́ gbogbo ohun tí ẹ̀ ń sọ sí àwọn òkè Israẹli, pé wọ́n ti di ahoro ati ìkógun fun yín. Ẹ̀ ń fi ẹnu yín sọ̀rọ̀ ìgbéraga sí mi, ẹ sì ń dá àpárá lù mí; gbogbo rẹ̀ ni mo gbọ́.’ ” OLUWA Ọlọrun ní, “N óo sọ ìwọ Edomu di ahoro, kí gbogbo ayé lè yọ̀ ọ́; bí o ti yọ ilẹ̀ Israẹli nígbà tí ilé wọn di ahoro. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe sí ọ, ìwọ náà óo di ahoro. Gbogbo òkè Seiri ati gbogbo ilẹ̀ Edomu yóo di ahoro. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” OLUWA ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, fi àsọtẹ́lẹ̀ bá àwọn òkè Israẹli wí. Sọ pé, ‘Ẹ̀yin òkè Israẹli, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí: Àwọn ọ̀tá ń yọ̀ yín, wọ́n ń sọ pé, àwọn òkè àtijọ́ ti di ogún àwọn.’ “Nítorí náà, ó ní kí n sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé òun OLUWA Ọlọrun ní nítorí pé wọ́n ti sọ ẹ̀yin òkè Israẹli di ahoro, wọ́n sì ja yín gbà lọ́tùn-ún lósì, títí tí ẹ fi di ìkógun fún àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, àwọn eniyan sì ń sọ ọ̀rọ̀ yín ní ìsọkúsọ, nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí èmi OLUWA wí, kí ẹ̀yin òkè ńláńlá ati ẹ̀yin òkè kéékèèké Israẹli, ẹ̀yin ipa odò ati ẹ̀yin àfonífojì, ẹ̀yin ibi tí ẹ ti di aṣálẹ̀ ati ẹ̀yin ìlú tí ẹ ti di ahoro, ẹ̀yin ìlú tí ẹ di ìjẹ ati yẹ̀yẹ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí wọ́n yi yín ká. “N óo fi ìtara sọ̀rọ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ati gbogbo Edomu, tí wọ́n fi tayọ̀tayọ̀ pẹlu ọkàn ìkórìíra sọ ilẹ̀ mi di ogún wọn, kí wọ́n lè gbà á, kí wọ́n sì pín in mọ́wọ́, nítorí wọ́n rò pé ilẹ̀ mi ti di tiwọn. “Nítorí náà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ Israẹli. Wí fún àwọn òkè ńláńlá ati àwọn òkè kéékèèké, ati àwọn ipa odò ati àwọn àfonífojì, pé èmi OLUWA Ọlọrun ní ìtara ati ìgbónára ni mo fi ń sọ̀rọ̀ nítorí pé ẹ ti jìyà pupọ, ẹ sì ti di ẹni ẹ̀gàn lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè yòókù. Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun, ń ṣe ìbúra pé, àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà ní àyíká yín yóo di ẹni ẹ̀sín. Ṣugbọn ẹ̀yin òkè Israẹli, igi óo hù lórí yín, wọn óo sì so èso fún Israẹli, àwọn eniyan mi, nítorí pé wọn kò ní pẹ́ pada wálé. Nítorí pé mo wà fun yín, n óo ṣí ojú àánú wò yín, wọn óo dá oko sórí yín, wọn óo sì gbin nǹkan sinu rẹ̀. N óo sọ àwọn ọmọ Israẹli tí ń gbé orí yín di pupọ. Àwọn ìlú yóo rí ẹni máa gbé inú wọn, wọn óo sì tún gbogbo ibi tí ó ti wó kọ́. N óo sọ eniyan ati ẹran ọ̀sìn di pupọ lórí yín, wọn óo máa bímọlémọ, wọn ó sì di ọ̀kẹ́ àìmọye. N óo mú kí eniyan máa gbé orí yín bí ìgbà àtijọ́, nǹkan ó sì dára fun yín ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. Ẹ óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA. N óo jẹ́ kí àwọn eniyan mi, àní àwọn ọmọ Israẹli, máa rìn bọ̀ lórí yín. Àwọn ni wọn óo ni yín, ẹ óo sì di ogún wọn, ẹ kò ní pa wọ́n lọ́mọ mọ́. “Nítorí àwọn eniyan ń wí pé ò ń paniyan, ati pé ò ń run àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè rẹ. Nítorí náà, o kò ní pa eniyan mọ́, o kò sì ní pa àwọn eniyan rẹ lọ́mọ mọ́, Èmi OLUWA Ọlọrun ni ó sọ bẹ́ẹ̀. N kò ní jẹ́ kí o gbọ́ ẹ̀gàn àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn mọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan kò ní dójútì ọ́ mọ́, n kò sì ní mú kí orílẹ̀-èdè rẹ kọsẹ̀ mọ́. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ń gbé ilẹ̀ wọn, wọ́n fi ìwà burúkú ba ilẹ̀ náà jẹ́. Lójú mi, ìwà wọn dàbí ìríra obinrin tí ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀ lọ́wọ́. Mo bá bínú sí wọn gan-an nítorí ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n ta sílẹ̀ ní ilẹ̀ náà ati oriṣa tí wọ́n fi bà á jẹ́. Mo fọ́n wọn ká sáàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, wọ́n sì tú káàkiri orí ilẹ̀ ayé. Ìwà ati ìṣe wọn ni mo fi dá wọn lẹ́jọ́. Nígbà tí wọ́n dé orílẹ̀-èdè tí mo fọ́n wọn ká sí, wọ́n bà mí lórúkọ jẹ́, nítorí àwọn eniyan ń sọ nípa wọn pé, ‘Eniyan OLUWA ni àwọn wọnyi, sibẹsibẹ wọ́n kúrò lórí ilẹ̀ OLUWA.’ Ṣugbọn mo ní ìtara fún orúkọ mímọ́ mi, tí àwọn ọmọ Israẹli sọ di nǹkan yẹ̀yẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà. “Nítorí náà, OLUWA ní kí n pe ẹ̀yin, ọmọ Israẹli, kí n sọ fun yín pé, òun OLUWA Ọlọrun ní, Kì í ṣe nítorí tiyín ni mo fi ń ṣe ohun tí mò ń ṣe, bíkòṣe nítorí orúkọ mímọ́ mi, tí ẹ̀ ń bàjẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ sálọ. N óo fihàn bí orúkọ ńlá mi, tí ó ti bàjẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè ti jẹ́ mímọ́ tó, àní orúkọ mi tí ẹ bàjẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ wà. Wọn yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun, nígbà tí mo bá ti ipasẹ̀ yín fi bí orúkọ mi ti jẹ́ mímọ́ tó hàn wọ́n. Nítorí pé n óo ko yín jáde láti inú àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, n óo gba yín jọ láti gbogbo ilẹ̀ ayé, n óo sì mu yín pada sórí ilẹ̀ yín. N óo wọ́n omi mímọ́ si yín lórí, àìmọ́ yín yóo sì di mímọ́. N óo wẹ̀ yín mọ́ kúrò ninu gbogbo ìbọ̀rìṣà yín. N óo fun yín ní ọkàn titun, n óo sì fi ẹ̀mí titun si yín ninu. N óo yọ ọkàn tí ó le bí òkúta kúrò, n óo sì fun yín ní ọkàn tí ó rọ̀ bí ẹran ara. N óo fi ẹ̀mí mi si yín ninu, n óo mú kí ẹ máa rìn ní ìlànà mi, kí ẹ sì máa fi tọkàntọkàn pa òfin mi mọ́. Ẹ óo sì máa gbé orí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín. Ẹ óo jẹ́ eniyan mi, n óo sì máa jẹ́ Ọlọrun yín. N óo gbà yín kúrò ninu gbogbo ìwà èérí yín. N óo mú ọkà pọ̀ ní ilé yín, n kò sì ní jẹ́ kí ìyàn mu yín mọ́. N óo jẹ́ kí èso igi ati èrè oko pọ̀, tóbẹ́ẹ̀ tí ìtìjú kò ní ba yín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mọ́ nítorí ìyàn. Nígbà náà ni ẹ óo ranti ìrìnkurìn ati ìwà burúkú yín, ara yín óo sì su yín nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín ati ìwà ìríra yín. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájú pé kì í ṣe nítorí yín ni n óo fi ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ kí ojú tì yín, kí ẹ sì dààmú nítorí ìwà yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli. Èmi OLUWA Ọlọrun, ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA Ọlọrun ní, “Ní ọjọ́ tí mo bá wẹ̀ yín mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ yín, n óo jẹ́ kí àwọn eniyan máa gbé inú àwọn ìlú yín, n óo sì mú kí wọ́n tún àwọn ibi tí ó wó lulẹ̀ kọ́. A óo dá oko sórí àwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti di igbó, dípò kí ó máa wà ní igbó lójú àwọn tí wọn ń kọjá lọ. Wọn yóo wí pé, ‘Ilẹ̀ yìí, tí ó ti jẹ́ igbó nígbà kan rí, ti dàbí ọgbà Edẹni, àwọn eniyan sì ti ń gbé àwọn ìlú tí wọ́n ti wó lulẹ̀, tí wọ́n ti di ahoro, tí wọ́n sì ti run tẹ́lẹ̀; a sì ti mọ odi wọn pada.’ Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà ní àyíká yín yóo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi OLUWA ni mo tún àwọn ibùgbé yín tí ó wó lulẹ̀ kọ́, tí mo sì tún gbin nǹkan ọ̀gbìn sí ilẹ̀ yín tí ó di igbó. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n óo sì ṣe.” OLUWA Ọlọrun ní, “Ohun kan tí n óo tún mú kí àwọn ọmọ Israẹli bèèrè lọ́wọ́ mi pé kí n ṣe fún àwọn ni pé kí n máa mú kí àwọn ọmọ wọn pọ̀ sí i bí ọ̀wọ́ aguntan. Kí wọn pọ̀ bí ọ̀wọ́ ẹran, àní bí ọ̀wọ́ ẹran ìrúbọ tíí pọ̀ ní Jerusalẹmu ní àkókò àjọ̀dún. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìlú tí a ti wó palẹ̀ yóo kún fún ọ̀pọ̀ eniyan. Wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” Agbára OLUWA sọ̀kalẹ̀ sára mi, ẹ̀mí rẹ̀ sì gbé mi wá sinu àfonífojì tí ó kún fún egungun. Ó mú mi la ààrin wọn kọjá; àwọn egungun náà pọ̀ gan-an ninu àfonífojì náà; wọ́n sì ti gbẹ. OLUWA bá bi mí léèrè, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, ǹjẹ́ àwọn egungun wọnyi lè tún jí?” Mo bá dáhùn, mo ní, “OLUWA, ìwọ nìkan ni o mọ̀.” Ó bá sọ fún mi pé, “Sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún àwọn egungun wọnyi, kí o wí fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin egungun gbígbẹ wọnyi, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí’. Ó ní: ‘N óo mú kí èémí wọ inú yín, ẹ óo sì di alààyè. N óo fi iṣan bò yín lára; lẹ́yìn náà n óo fi ara ẹran bò yín, n óo sì da awọ bò yín lára. N óo wá fi èémí si yín ninu, ẹ óo di alààyè, ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’ ” Mo bá sọ àsọtẹ́lẹ̀ bí OLUWA ti pàṣẹ fún mi. Bí mo ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ tán, mo bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ ariwo ati ìrọ́kẹ̀kẹ̀, àwọn egungun náà sì bẹ̀rẹ̀ sí so mọ́ ara wọn; egungun ń so mọ́ egungun. Kí n tó ṣẹ́jú pẹ́, iṣan ti dé ara wọn, ẹran ti bo iṣan, awọ ara sì ti bò wọ́n, ṣugbọn kò tíì sí èémí ninu wọn. OLUWA bá sọ fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún èémí, sọ fún un pé OLUWA Ọlọrun ní: ‘Wá, ìwọ èémí láti orígun mẹrẹẹrin ilẹ̀ ayé, kí o fẹ́ sinu àwọn òkú wọnyi, kí wọ́n di alààyè.’ ” Mo bá sọ àsọtẹ́lẹ̀ bí ó ti pàṣẹ fún mi. Èémí wọ inú wọn, wọ́n sì di alààyè; ogunlọ́gọ̀ eniyan ni wọ́n, wọ́n bá dìde dúró! OLUWA bá sọ fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, àwọn ọmọ Israẹli ni àwọn egungun wọnyi. Wọ́n ń sọ pé, ‘Egungun wa ti gbẹ; kò sí ìrètí fún wa mọ́, a ti pa wá run patapata.’ Nítorí náà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ kí o wí fún wọn pé OLUWA Ọlọrun ní, ‘N óo ṣí ibojì yín; n óo sì gbe yín dìde, ẹ̀yin eniyan mi, n óo mu yín pada sí ilé, ní ilẹ̀ Israẹli. Ẹ̀yin eniyan mi, nígbà tí mo bá ṣí ibojì yín, tí mo sì gbe yín dìde, ẹ óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA. N óo fi ẹ̀mí mi sinu yín, ẹ óo sì tún wà láàyè; n óo sì mu yín wá sí ilẹ̀ yín. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo wí bẹ́ẹ̀, tí mo sì ṣe bẹ́ẹ̀.’ ” OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, mú igi kan kí o kọ sí ara rẹ̀ pé, ‘Igi Juda ati àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀.’ Mú igi mìíràn kí o kọ sí ara rẹ̀ pé, ‘Ti Josẹfu, (igi Efuraimu) ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀.’ Fi ẹnu wọn ko ara wọn, kí wọ́n di igi kan lọ́wọ́ rẹ. Bí àwọn eniyan rẹ bá bi ọ́ pé kí ni ìtumọ̀ ohun tí ò ń ṣe yìí? Wí fún wọn pé èmi OLUWA Ọlọrun ní: ‘N óo mú igi Josẹfu ati àwọn ìdílé Israẹli tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, n óo fi ẹnu rẹ̀ ko ẹnu igi Juda; n óo sọ wọ́n di igi kan, wọn yóo sì di ọ̀kan lọ́wọ́ mi.’ “Mú àwọn igi tí o kọ nǹkan sí lára lọ́wọ́, lójú wọn, kí o sọ fún wọn pé OLUWA Ọlọrun ní, ‘Ẹ wò ó! N óo kó àwọn ọmọ Israẹli jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà, n óo kó wọn jọ láti ibi gbogbo wá sí ilẹ̀ wọn. N óo sọ wọ́n di orílẹ̀-èdè kan ní orí òkè Israẹli, ọba kanṣoṣo ni yóo sì jẹ lé gbogbo wọn lórí. Wọn kò ní jẹ́ orílẹ̀-èdè meji mọ́; wọn kò ní pín ara wọn sí ìjọba meji mọ́. Wọn kò ní fi ìbọ̀rìṣà kankan, tabi ìwà ìríra kankan tabi ẹ̀ṣẹ̀ wọn, sọ ara wọn di aláìmọ́ mọ́. N óo gbà wọ́n ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ìfàsẹ́yìn tí wọ́n ti dá. N óo wẹ̀ wọ́n mọ́, wọn yóo máa jẹ́ eniyan mi, èmi náà óo sì jẹ́ Ọlọrun wọn. Dafidi, iranṣẹ mi ni yóo jọba lórí wọn; gbogbo wọn óo ní olùṣọ́ kan. Wọn óo máa pa òfin mi mọ́, wọn óo sì máa fi tọkàntọkàn rìn ní ìlànà mi. Wọn óo máa gbé ilẹ̀ tí mo fún Jakọbu iranṣẹ mi, ilẹ̀ tí àwọn baba ńlá yín gbé. Àwọn ati àwọn ọmọ wọn ati àwọn ọmọ ọmọ wọn yóo máa gbé ibẹ̀ títí lae. Dafidi iranṣẹ mi ni yóo sì jẹ́ ọba wọn títí lae. N óo bá wọn dá majẹmu alaafia, tí yóo jẹ́ majẹmu ayérayé. N óo bukun wọn, n óo jẹ́ kí wọn pọ̀ sí i, n óo sì gbé ilé mímọ́ mi kalẹ̀ sí ààrin wọn títí lae. N óo kọ́ ibùgbé mi sí ààrin wọn, n óo jẹ́ Ọlọrun wọn, wọn yóo sì jẹ́ eniyan mi. Àwọn orílẹ̀-èdè yòókù yóo wá mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo ya Israẹli sọ́tọ̀, nígbà tí ibi mímọ́ mi bá wà láàrin wọn títí lae.’ ” OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú sí Gogu, ní ilẹ̀ Magogu; tí ó jẹ́ olórí Meṣeki ati Tubali, kí o sì fi àsọtẹ́lẹ̀ bá a wí, pé OLUWA Ọlọrun ní, Mo lòdì sí ọ, ìwọ Gogu, olórí Meṣeki ati Tubali. N óo yí ojú rẹ pada, n óo fi ìwọ̀ kọ́ ọ lẹ́nu, n óo sì mú ọ jáde, pẹlu gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ, ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ, ati àwọn ati ẹṣin wọn, gbogbo wọn, tàwọn ti ihamọra wọn, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun tí wọ́n ní asà ati apata, tí wọ́n sì ń fi idà wọn. Àwọn ará Pasia, ati àwọn ará Kuṣi, ati àwọn ará Puti wà pẹlu rẹ̀; gbogbo wọn, tàwọn ti apata ati àṣíborí wọn. Gomeri ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ati Beti Togama láti òpin ilẹ̀ ìhà àríwá ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀; bẹ́ẹ̀ náà ni ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, wọ́n wà pẹlu rẹ̀. Dira ogun, kí o sì wà ní ìmúrasílẹ̀, ìwọ ati gbogbo eniyan tí wọ́n pé yí ọ ká, kí o jẹ́ olórí ẹ̀ṣọ́ fún wọn. Lẹ́yìn ọpọlọpọ ọjọ́ a óo ko yín jọ. Ní ọdún mélòó kan sí i, ẹ óo gbógun ti ilẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bọ̀ sípò lẹ́yìn ìparun ogun, orílẹ̀-èdè tí a ṣà jọ láti ààrin ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè mìíràn sórí àwọn òkè ńláńlá Israẹli, ilẹ̀ tí ó ti wà ní ahoro fún ọpọlọpọ ọdún. Láti inú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ni a ti ṣa àwọn eniyan rẹ̀ jọ; nisinsinyii, gbogbo wọn wà láìléwu. Ẹ óo gbéra, ẹ óo máa bọ̀ bí ìjì líle, ẹ óo dàbí ìkùukùu tí ó bo ilẹ̀, ìwọ ati gbogbo ọmọ ogun rẹ, pẹlu ọpọlọpọ eniyan tí ó wà pẹlu rẹ.” OLUWA Ọlọrun ní, “Ní ọjọ́ náà èròkerò yóo wá sí ọkàn rẹ, o óo wí ninu ara rẹ pé, ‘N óo gbógun ti ilẹ̀ tí kò ní odi yìí; n óo kọlu àwọn tí wọ́n jókòó jẹ́ẹ́jẹ́ wọn láìléwu, gbogbo wọn ń gbé ìlú tí kò ní odi, kò sì ní ìlẹ̀kùn, kí á má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn.’ N óo lọ kó wọn lẹ́rù, n óo sì kó ìkógun. N óo kọlu àwọn ilẹ̀ tí ó ti di ahoro nígbà kan rí, ṣugbọn tí àwọn eniyan ń gbé ibẹ̀ nisinsinyii, àwọn eniyan tí a ṣà jọ láti ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, ṣugbọn tí wọ́n ní mààlúù ati ohun ìní, tí wọ́n sì ń gbé ìkóríta ilẹ̀ ayé. Ṣeba ati Dedani ati àwọn oníṣòwò Taṣiṣi, ati àwọn ìlú agbègbè wọn yóo bi ọ́ pé, ‘Ṣé o wá kó ìkógun ni, ṣé o kó àwọn ọmọ ogun rẹ jọ láti wá kó ẹrú, fadaka ati wúrà, ati mààlúù, ọrọ̀ ati ọpọlọpọ ìkógun?’ ” Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní kí n fi àsọtẹ́lẹ̀ bá Gogu wí pé, OLUWA Ọlọrun ní: “Ní ọjọ́ tí àwọn eniyan mi, àwọn ọmọ Israẹli, bá ń gbé láìléwu, ìwọ óo gbéra ní ààyè rẹ ní ọ̀nà jíjìn, ní ìhà àríwá, ìwọ ati ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, gbogbo wọn lórí ẹṣin, ọpọlọpọ eniyan, àní, àwọn ọmọ ogun. O óo kọlu àwọn ọmọ Israẹli, àwọn eniyan mi, bí ìkùukùu tí ń ṣú bo ilẹ̀. Nígbà tí ó bá yà n óo mú kí o kọlu ilẹ̀ mi, kí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn lè mọ̀ mí nígbà tí mo bá ti ipasẹ̀ ìwọ Gogu fi bí ìwà mímọ́ mi ti rí hàn níṣojú wọn. OLUWA ní: ṣé ìwọ ni ẹni tí mo sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ìgbà àtijọ́ láti ẹnu àwọn wolii Israẹli, àwọn iranṣẹ mi, tí wọ́n ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún ọpọlọpọ ọdún pé n óo mú ọ wá láti gbógun tì wọ́n? “Ṣugbọn ní ọjọ́ tí Gogu bá gbógun ti ilẹ̀ Israẹli, inú mi óo ru. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Pẹlu ìtara ati ìrúnú ni mo fi ń sọ pé ilẹ̀ Israẹli yóo mì tìtì ní ọjọ́ náà. Àwọn ẹja inú omi, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, àwọn ẹranko inú igbó, gbogbo ohun tí ń rìn lórí ilẹ̀, ati gbogbo eniyan tí ó wà láyé yóo wárìrì. Àwọn òkè yóo wó lulẹ̀, àwọn òkè etí òkun yóo ṣubú sinu òkun. Gbogbo odi ìlú yóo sì wó lulẹ̀. N óo dá oríṣìíríṣìí ẹ̀rù ba Gogu, lórí òkè mi, àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yóo fa idà yọ sí ara wọn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo sì fi àjàkálẹ̀ àrùn ati ikú ogun ṣe ìdájọ́ wọn. N óo rọ òjò yìnyín, iná, ati imí ọjọ́ lé òun, ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ati ọpọlọpọ eniyan pupọ tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ lórí. N óo fi títóbi mi ati ìwà mímọ́ mi hàn lójú àwọn orílẹ̀-èdè, wọn yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” OLUWA Ọlọrun ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, fi àsọtẹ́lẹ̀ bá Gogu wí, sọ fún un pé OLUWA Ọlọrun ní: ‘Mo lòdì sí ọ́, ìwọ Gogu, ìwọ tí o jẹ́ olórí Meṣeki ati Tubali. N óo yí ọ pada, n óo lé ọ siwaju, n óo mú ọ wá láti òpin ìhà àríwá, o óo wá dojú kọ àwọn òkè Israẹli. Lẹ́yìn náà, n óo gbọn ọrun rẹ dànù lọ́wọ́ òsì rẹ; n óo sì gbọn ọfà bọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ. Ìwọ, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ, ati àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ yóo kú lórí àwọn òkè Israẹli. N óo fi yín ṣe oúnjẹ fún oniruuru àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko burúkú. Ninu pápá tí ó tẹ́jú ni ẹ óo kú sí; èmi OLUWA Ọlọrun, ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo rọ òjò iná lé Magogu lórí, ati àwọn tí wọn ń gbé láìléwu ní etí òkun, wọn yóo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA. N óo sọ orúkọ mímọ́ mi di mímọ̀ láàrin àwọn eniyan mi àwọn ọmọ Israẹli, n kò ní jẹ́ kí wọ́n ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mọ́, àwọn orílẹ̀-èdè yòókù yóo sì mọ̀ pé èmi OLUWA, ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.’ ” OLUWA Ọlọrun ní, “Ẹ wò ó! Ọjọ́ tí mo ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ ń bọ̀, yóo dé. Àwọn ará ìlú Israẹli yóo tú síta, wọn yóo dáná sun àwọn ohun ìjà ogun: apata ati asà, ọrun ati ọfà, àáké ati ọ̀kọ̀. Ọdún meje ni wọn yóo fi dáná sun wọ́n. Fún ọdún meje yìí, ẹnìkan kò ní ṣẹ́ igi ìdáná lóko, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní gé igi ninu igbó kí wọ́n tó dáná; ohun ìjà ogun ni wọn yóo máa fi dáná. Wọn yóo kó ẹrù àwọn tí wọ́n ti kó wọn lẹ́rù rí; wọn yóo fi ogun kó àwọn ìlú tí wọ́n ti fi ogun kó wọn rí. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA ní, “Tí ó bá di ìgbà náà, n óo fún Gogu ní ibi tí wọn yóo sin ín sí ní Israẹli, àní àfonífojì àwọn arìnrìnàjò tí ó wà ní ìlà oòrùn Òkun Iyọ̀. Yóo dínà mọ́ àwọn arìnrìnàjò nítorí níbẹ̀ ni a óo sin Gogu ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ sí. A óo sì máa pè é ní àfonífojì Hamoni Gogu. Oṣù meje ni yóo gba àwọn ọmọ Israẹli láti sin òkú wọn, kí wọ́n baà lè fọ ilẹ̀ náà mọ́. Gbogbo àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà ni yóo sin wọ́n, wọn óo sì gbayì ní ọjọ́ náà, nígbà tí mo bá fi ògo mi hàn. OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn oṣù meje wọn yóo yan àwọn kan tí wọn óo la ilẹ̀ náà já, tí wọn óo máa wá òkú tí ó bá kù nílẹ̀, tí wọn óo sì máa sin wọ́n kí wọ́n lè sọ ilẹ̀ náà di mímọ́. Bí ẹnìkan ninu àwọn tí ń wá òkú kiri bá rí egungun eniyan níbìkan, yóo fi àmì sibẹ títí tí àwọn tí ń sin òkú yóo fi wá sin ín ní àfonífojì Hamoni Gogu. Ìlú kan yóo wà níbẹ̀ tí yóo máa jẹ́ Hamoni. Bẹ́ẹ̀ ni wọn yóo ṣe fọ ilẹ̀ náà mọ́.” OLUWA Ọlọrun ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, ké pe oniruuru ẹyẹ ati gbogbo ẹranko igbó, kí o sọ fún wọn pé, ‘Ẹ gbá ara yín jọ, kí ẹ máa bọ̀ láti gbogbo àyíká tí ẹ wà. Ẹ wá sí ibi ẹbọ ńlá tí mo fẹ́ ṣe fun yín lórí àwọn òkè Israẹli. Ẹ óo jẹ ẹran, ẹ óo sì mu ẹ̀jẹ̀. Ẹ óo jẹ ẹran ara àwọn akikanju, ẹ óo sì mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ọba ilẹ̀ ayé, bíi ti àgbò, ati ọ̀dọ́ aguntan, ati ewúrẹ́ ati àwọn mààlúù rọ̀bọ̀tọ̀ Baṣani. Ẹ óo jẹ ọ̀rá ní àjẹyó, ẹ óo sì mu ẹ̀jẹ̀ ní àmuyó ní ibi àsè tí n óo sè fun yín. Ẹ óo jẹ ẹṣin ati àwọn tí wọn ń gùn wọ́n, àwọn alágbára ati oríṣìíríṣìí àwọn ọmọ ogun níbi àsè tí n óo sè fun yín.’ Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “N óo fi ògo mi hàn láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo wọn ni yóo sì rí irú ẹjọ́ tí mo dá wọn ati irú ìyà tí mo fi jẹ wọ́n. Láti ìgbà náà lọ, àwọn ọmọ Israẹli óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli dá tí wọ́n fi di ẹni tí ó lọ sí ìgbèkùn, ati pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí mi ni mo ṣe dijú sí wọn, tí mo fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, tí wọ́n sì fi idà pa wọ́n. Bí àìmọ́ ati ẹ̀ṣẹ̀ wọn ti pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni mo fìyà jẹ wọ́n tó, mo sì gbé ojú mi kúrò lọ́dọ̀ wọn.” Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “N óo ṣàánú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli n óo kó àwọn ọmọ Jakọbu pada láti oko ẹrú, n óo ṣàánú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, n óo sì jowú nítorí orúkọ mímọ́ mi. Wọn yóo gbàgbé ìtìjú wọn ati ìwà ọ̀tẹ̀ tí wọn hù sí mi, nígbà tí wọn bá ń gbé orí ilẹ̀ wọn láìléwu, tí kò sì sí ẹni tí yóo dẹ́rùbà wọ́n. Nígbà tí mo bá kó wọn pada láti inú oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè, tí mo kó wọn jọ láti ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn, n óo fi ara mi hàn bí ẹni mímọ́ lójú ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè. Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn, nítorí pé mo kó wọn lọ sí ìgbèkùn láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, mo sì tún kó wọn pada sí ilẹ̀ wọn. N kò ní fi ọ̀kankan ninu wọn sílẹ̀ sí ààrin orílẹ̀-èdè mìíràn mọ́. N óo tú ẹ̀mí mi lé àwọn ọmọ Israẹli lórí, n ko ní gbé ojú mi kúrò lọ́dọ̀ wọn mọ́. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù kinni, ọdún kẹẹdọgbọn tí a ti wà ní ìgbèkùn, tíí ṣe ọdún kẹrinla tí ogun fọ́ ìlú Jerusalẹmu, agbára OLUWA sọ̀kalẹ̀ sára mi. Ó mú mi lọ sí ilẹ̀ Israẹli ninu ìran, ó gbé mi sí orí òkè gíga kan. Ó dàbí ẹni pé ìlú kan wà ní ìhà ìsàlẹ̀ òkè náà. Nígbà tí ó mú mi dé ìlú náà, mo rí ọkunrin kan tí àwọ̀ rẹ̀ dàbí idẹ. Ó sì dúró lẹ́nu ọ̀nà, ó mú okùn òwú ati ọ̀pá tí wọ́n fi ń wọn nǹkan lọ́wọ́. Ọkunrin yìí bá pè mí, ó ní: “ìwọ ọmọ eniyan, ya ojú rẹ, kí o máa wòran, ya etí rẹ sílẹ̀, kí o máa gbọ́; sì fi ọkàn sí gbogbo ohun tí n óo fihàn ọ́; nítorí kí n baà lè fihàn ọ́ ni a ṣe mú ọ wá síbí. Gbogbo ohun tí o bá rí ni o gbọdọ̀ sọ fún àwọn ọmọ Israẹli.” Mo rí ògiri kan tí ó yí ibi tí tẹmpili wà ká. Ọ̀pá ìwọnlẹ̀ tí ó wà lọ́wọ́ ọkunrin tí mo kọ́ rí gùn ní igbọnwọ mẹfa. Igbọnwọ kọ̀ọ̀kan ọ̀pá tirẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan ati ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan, (ìdajì mita kan). Ó sì wọn ògiri náà. Ó fẹ̀ ní ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ kan, ó sì ga ní ọ̀pá kan, (mita 3). Lẹ́yìn náà ó lọ sí ẹnu ọ̀nà tí ó kọjú sí ìhà ìlà oòrùn, ó gun àtẹ̀gùn tí ó wà níbẹ̀, ó sì wọn àbáwọlé ẹnu ọ̀nà náà; ó jìn ní ìwọ̀n ọ̀pá kan, (mita 3). Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ náà gùn ní ìwọ̀n ọ̀pá kan, wọ́n sì fẹ̀ ní ìwọ̀n ọ̀pá kan. Àlàfo tí ó wà láàrin àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ náà jẹ́ igbọnwọ marun-un (mita 2½). Àbáwọlé ẹnu ọ̀nà ẹ̀bá ìloro tí ó kọjú sí tẹmpili jẹ́ ọ̀pá kan. Lẹ́yìn náà ó wọn ìloro ẹnu ọ̀nà tí ó wà ninu, ó jẹ́ igbọnwọ mẹjọ (mita 4), àtẹ́rígbà rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji, mita kan. Ìloro ẹnu ọ̀nà náà wà ninu patapata. Yàrá mẹta mẹta wà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ẹnu ọ̀nà náà. Bákan náà ni ìwọ̀n àwọn yàrá mẹtẹẹta rí. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìwọ̀n àtẹ́rígbà wọn, ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji. Lẹ́yìn náà, ó wọn ìbú àbáwọlé ẹnu ọ̀nà, ó jẹ́ igbọnwọ mẹ́wàá (mita 5). Ó wọn gígùn ẹnu ọ̀nà náà, ó jẹ́ igbọnwọ mẹtala (mita 6½). Ògiri kan wà níwájú àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ náà, ó ga ní igbọnwọ kan ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji. Ati òòró ati ìbú àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ náà jẹ́ igbọnwọ mẹfa mẹfa (mita 3). Ó wọn ẹnu ọ̀nà náà láti ẹ̀yìn àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ kan títí dé ẹ̀yìn yàrá ẹ̀gbẹ́ keji, ìbú rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½), láti ìlẹ̀kùn kinni sí ekeji. Ó tún wọn ìloro, ó jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). Gbọ̀ngàn kan yí ìloro ẹnu ọ̀nà ká láti iwájú ẹnu ọ̀nà ní àbáwọlé, títí kan ìloro ẹnu ọ̀nà tí ó wà ninu, jẹ́ aadọta igbọnwọ (mita 25). Ẹnu ọ̀nà náà ní àwọn fèrèsé tóóró tóóró yíká, tí ó ga kan àwọn àtẹ́rígbà àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́. Bákan náà, ìloro náà ní àwọn fèrèsé yíká, àwòrán ọ̀pẹ sì wà lára àtẹ́rígbà rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó mú mi wá sí ibi gbọ̀ngàn ti òde, mo rí àwọn yàrá ati pèpéle yíká àgbàlá náà. Ọgbọ̀n yàrá ni ó wà lára àgbàlá náà. Pèpéle kan wà níbi ẹnu ọ̀nà, tí gígùn rẹ̀ rí bákan náà pẹlu ẹnu ọ̀nà, èyí ni pèpéle tí ó wà ní ìsàlẹ̀. Ó wọn ibẹ̀ láti inú ẹnu ọ̀nà kúkúrú títí dé iwájú ìta gbọ̀ngàn inú, ó jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ, (mita 45), ní ìhà ìlà oòrùn ati ìhà àríwá. Lẹ́yìn náà, ó ṣiwaju mi lọ sí ìhà àríwá; ó wọn ìbú ati òòró ẹnu ọ̀nà kan tí ó wà níbẹ̀ tí ó kọjú sí ìhà àríwá, tí ó sì ṣí sí àgbàlá òde. Àwọn yàrá mẹta mẹta wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji. Àtẹ́rígbà ati ìloro rẹ̀ rí bákan náà pẹlu àwọn ti ẹnu ọ̀nà àkọ́kọ́. Òòró rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ, (mita 25), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½). Àwọn fèrèsé rẹ̀, ati ìloro rẹ̀ ati àwọn àwòrán ọ̀pẹ ara rẹ̀ rí bíi àwọn ti ẹnu ọ̀nà tí ó kọjú sí ìlà oòrùn. Ó ní àtẹ̀gùn meje, ìloro rẹ̀ sì wà ninu. Níwájú ẹnu ọ̀nà ìhà àríwá, ni ẹnu ọ̀nà gbọ̀ngàn inú wà bí ó ti wà níwájú ẹnu ọ̀nà ti ìlà oòrùn. Ọkunrin náà wọn ibẹ̀ láti ẹnu ọ̀nà kan sí ikeji, ó jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45). Ó mú mi lọ sí apá ìhà gúsù, mo sì rí ẹnu ọ̀nà kan níbẹ̀. Ó wọn àtẹ́rígbà ati ìloro rẹ̀, wọ́n sì rí bákan náà pẹlu àwọn yòókù. Fèrèsé yí inú ati ìloro rẹ̀ ká, bíi àwọn fèrèsé ti àwọn ẹnu ọ̀nà yòókù. Òòró rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ (mita 25), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½). Ó ní àtẹ̀gùn meje, ìloro rẹ̀ wà ninu, àwòrán ọ̀pẹ sì wà lára àtẹ́rígbà rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji. Ẹnu ọ̀nà kan wà ní ìhà gúsù gbọ̀ngàn inú. Ó wọn ibẹ̀, láti ẹnu ọ̀nà náà sí ẹnu ọ̀nà tí ó wà ní ìhà gúsù, jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45). Lẹ́yìn náà, ó mú mi wá sí ibi gbọ̀ngàn inú, lẹ́bàá ẹnu ọ̀nà ìhà gúsù, ó sì wọn ẹnu ọ̀nà náà, bákan náà ni òòró ati ìbú rẹ̀ pẹlu àwọn yòókù. Bákan náà sì ni àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, àtẹ́rígbà rẹ̀ ati ìloro rẹ̀ pẹlu àwọn yòókù. Fèrèsé wà lára rẹ̀ yíká ninu, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìloro rẹ̀. Òòró rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ (mita 25), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½). Àwọn ìloro wà yí i ká, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gùn ní igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½), wọ́n sì fẹ̀ ní igbọnwọ marun-un (mita 2½). Ìloro rẹ̀ kọjú sí gbọ̀ngàn òde, àwòrán ọ̀pẹ wà lára àtẹ́rígbà rẹ̀, àtẹ̀gùn rẹ̀ sì ní ìgbésẹ̀ mẹjọ. Lẹ́yìn náà, ó mú mi lọ sí ìhà ìlà oòrùn gbọ̀ngàn inú, ó sì wọn ẹnu ọ̀nà rẹ̀, bákan náà ni ó rí pẹlu àwọn yòókù. Bákan náà sì ni àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, ati àtẹ́rígbà, ati ìloro rẹ̀ rí pẹlu àwọn yòókù, fèrèsé wà lára òun náà yíká ninu, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìloro rẹ̀. Òòró rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ (mita 25), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½). Ìloro rẹ̀ kọjú sí gbọ̀ngàn òde, àwòrán ọ̀pẹ wà lára àtẹ́rígbà rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji, àtẹ̀gùn rẹ̀ sì ní ìgbésẹ̀ mẹjọ. Lẹ́yìn náà, ó mú mi lọ sí ibi ẹnu ọ̀nà tí ó wà ní ìhà àríwá, ó sì wọ̀n ọ́n, bákan náà ni òun náà rí pẹlu àwọn yòókù. Bákan náà ni àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, àtẹ́rígbà rẹ̀ ati ìloro rẹ̀ rí pẹlu àwọn yòókù, ó sì ní fèrèsé yíká. Òòró rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ (mita 25), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½). Ìloro rẹ̀ kọjú sí gbọ̀ngàn òde, àwòrán ọ̀pẹ wà lára àtẹ́rígbà rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji, àtẹ̀gùn rẹ̀ sì ní ìgbésẹ̀ mẹjọ. Yàrá kan wà tí ìlẹ̀kùn rẹ̀ wà ninu ìloro ẹnu ọ̀nà, níbẹ̀ ni wọ́n tí ń fọ ẹran tí wọ́n bá fẹ́ fi rú ẹbọ sísun. Tabili meji meji wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji ìloro ẹnu ọ̀nà náà, lórí wọn ni wọ́n tí ń pa àwọn ẹran ẹbọ sísun, ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi. Tabili meji wà ní ìta ìloro náà, ní ẹnu ọ̀nà ti ìhà àríwá, tabili meji sì tún wà ní ẹ̀gbẹ́ keji ìloro ẹnu ọ̀nà náà. Tabili mẹrin wà ninu, mẹrin sì wà ní ìta, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnu ọ̀nà; gbogbo rẹ̀ jẹ́ tabili mẹjọ. Lórí wọn ni wọ́n tí ń pa ẹran ìrúbọ. Tabili mẹrin kan tún wà tí wọ́n fi òkúta gbẹ́, tí wọn ń lò fún ẹbọ sísun. Òòró rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀ (mita 7), ìbú rẹ̀ náà jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀ (mita 7), ó sì ga ní igbọnwọ kan (bíi ìdajì mita). Lórí rẹ̀ ni wọ́n ń kó àwọn ohun tí wọ́n fi ń pa ẹran ẹbọ sísun ati ti ẹbọ yòókù sí. Wọ́n kan àwọn ìkọ́ kan tí ó gùn ní ìwọ̀n àtẹ́lẹwọ́ kan mọ́ ara tabili yíká ninu. Wọn a máa gbé ẹran tí wọn yóo bá fi rúbọ lé orí àwọn tabili náà. Lẹ́yìn náà ó mú mi wọ gbọ̀ngàn ti inú. Mo rí yàrá meji ninu gbọ̀ngàn yìí: ọ̀kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnu ọ̀nà ìhà àríwá, ó dojú kọ ìhà gúsù, ekeji wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìhà gúsù, ó dojú kọ ìhà àríwá. Ó wí fún mi pé àwọn alufaa tí ń mójútó tẹmpili ni wọ́n ni yàrá tí ó kọjú sí ìhà gúsù. Yàrá tí ó kọjú sí ìhà àríwá jẹ́ ti àwọn alufaa tí wọn ń mójútó pẹpẹ; àwọn ni àwọn ọmọ Sadoku. Àwọn nìkan ninu ìran Lefi ni wọ́n lè súnmọ́ OLUWA láti rúbọ sí i. Ó wọn gbọ̀ngàn ti inú, òòró rẹ̀ jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45), igun rẹ̀ mẹrẹẹrin dọ́gba, pẹpẹ sì wà níwájú tẹmpili. Lẹ́yìn náà, ó mú mi lọ sí ìloro tẹmpili, ó sì wọn àtẹ́rígbà rẹ̀. Ó jẹ́ igbọnwọ marun-un marun-un (mita 2½), ní ẹ̀gbẹ́ kinni ati ikeji; ìbú ẹnu ọ̀nà náà jẹ́ igbọnwọ mẹrinla (mita 7). Àwọn ògiri rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ mẹta mẹta (mita 1½), ní ẹ̀gbẹ́ kinni ati ikeji. Òòró ìloro náà jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mejila (mita 5½), àtẹ̀gùn rẹ̀ ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá, òpó sì wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji àtẹ́rígbà rẹ̀. Lẹ́yìn náà ó mú mi lọ sí ibi mímọ́, ó wọn àtẹ́rígbà rẹ̀, ìbú rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji jẹ́ igbọnwọ mẹfa (mita 3). Ìbú ẹnu ọ̀nà àbáwọlé jẹ́ igbọnwọ mẹ́wàá (mita 5), ògiri ẹnu ọ̀nà àbáwọlé náà gùn ní igbọnwọ marun-un marun-un (mita 3), lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji. Ó wọn ibi mímọ́ inú náà: òòró rẹ̀ jẹ́ ogoji igbọnwọ (mita 20), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 10). Lẹ́yìn náà, ó wọ yàrá inú lọ, ó wọn àtẹ́rígbà ẹnu ọ̀nà, ó jẹ́ igbọnwọ meji (bíi mita kan), ìbú ẹnu ọ̀nà àbáwọlé náà jẹ́ igbọnwọ mẹfa (mita 3), ògiri ẹnu ọ̀nà àbáwọlé náà sì gùn ní igbọnwọ meje (mita 3½). Ó wọn òòró yàrá náà, ó jẹ́ ogún igbọnwọ, (mita 10), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 10), níwájú ibi mímọ́ náà. Ó sì wí fún mi pé ìhín ni ibi mímọ́ jùlọ. Lẹ́yìn náà, ó wọn ògiri tẹmpili, ó nípọn ní igbọnwọ mẹfa (mita 3), ìbú àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ jẹ́ igbọnwọ mẹrin (bíi mita 2) yípo Tẹmpili náà. Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ náà jẹ́ alágbèékà mẹta, ọgbọ̀n yàrá ni ó sì wà ninu àgbékà kọ̀ọ̀kan. Wọ́n mọ òpó sí ara ògiri Tẹmpili yíká, kí wọn baà lè gba àwọn yàrá dúró kí ó má baà jẹ́ pé ògiri Tẹmpili ni óo gbé wọn ró. Àwọn yàrá náà ń fẹ̀ sí i láti àgbékà dé àgbékà, bí òpó tí wọ́n mọ sí ara ògiri Tẹmpili ṣe ń tóbi sí i. Àtẹ̀gùn kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Tẹmpili náà tí ó lọ sókè. Ó bẹ̀rẹ̀ láti àgbékà kinni, ó gba inú ti ààrin lọ sí èyí tí ó wà lókè patapata. Mo rí i pé Tẹmpili náà ní pèpéle tí ó ga yíká. Ìpìlẹ̀ àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ jẹ́ ọ̀pá kan tí ó gùn ní igbọnwọ gígùn mẹfa (mita 3). Ògiri ìta àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ nípọn ní igbọnwọ marun-un (mita 2½), apá kan pèpéle tí kò ní ohunkohun lórí jẹ́ igbọnwọ marun-un. Láàrin pèpéle Tẹmpili ati àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ gbọ̀ngàn fẹ̀ ní ogún igbọnwọ (mita 10), yíká gbogbo ẹ̀gbẹ́ tẹmpili. Àwọn ìlẹ̀kùn àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ ṣí sí apá pèpéle tí kò sí ohunkohun lórí rẹ̀. Ìlẹ̀kùn kan kọjú sí ìhà àríwá, ekeji kọjú sí ìhà gúsù. Ìbú pèpéle tí kò sí ohunkohun lórí rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ marun-un (mita 2½) yíká. Ilé tí ó kọjú sí àgbàlá Tẹmpili ní apá ìwọ̀ oòrùn fẹ̀ ní aadọrin igbọnwọ (mita 35), ògiri ilé náà nípọn ní igbọnwọ marun-un (mita 2½) yíká, òòró rẹ̀ sì jẹ́ aadọrun-un igbọnwọ (mita 45). Lẹ́yìn náà, ó wọn Tẹmpili, ó gùn ní ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45). Àgbàlá ati ilé náà pẹlu ògiri rẹ̀ gùn ní ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45). Bákan náà ni gígùn iwájú tẹmpili tí ó kọjú sí ìlà oòrùn ati àgbàlá, òun náà jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45). Lẹ́yìn náà, ó wọn òòró ilé ní ìhà tí ó dojú kọ àgbàlá tí ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn ati àwọn ògiri rẹ̀; ẹ̀gbẹ́ kinni keji gùn ní ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45). Pákó fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ ni wọ́n fi bo ara ògiri ibi mímọ́ jùlọ Tẹmpili náà ati yàrá inú ati ìloro ti ìta yíká. Àwọn mẹtẹẹta ní fèrèsé aláṣìítì. Wọ́n fi pákó fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ bo ara ògiri Tẹmpili náà yíká láti ilẹ̀ títí kan ibi fèrèsé, títí kọjá ìloro. (Wọ́n fi pákó bo àwọn fèrèsé náà). Ati ààyè tí ó wà lókè ẹnu ọ̀nà, títí kan yàrá inú pàápàá, ati ẹ̀yìn ìta. Gbogbo ara ògiri yàrá inú yíká ati ibi mímọ́ ni wọ́n gbẹ́ àwòrán igi ọ̀pẹ ati kerubu sí yíká; wọ́n gbẹ́ igi ọ̀pẹ kọ̀ọ̀kan sí ààrin kerubu meji meji. Kerubu kọ̀ọ̀kan ní iwájú meji meji. Iwájú tí ó dàbí ti eniyan kọjú sí igi ọ̀pẹ ní ẹ̀gbẹ́ kinni, ekeji tí ó dàbí ti ọ̀dọ́ kinniun kọjú sí igi ọ̀pẹ ní ẹ̀gbẹ́ keji. Wọ́n gbẹ́ wọn bẹ́ẹ̀ sí ara Tẹmpili yíká. Wọ́n gbẹ́ àwòrán igi ọ̀pẹ ati kerubu sí ara ògiri náà láti ilẹ̀ títí dé òkè ìlẹ̀kùn. Àwọn òpó ìlẹ̀kùn gbọ̀ngàn ti òde ibi mímọ́ jùlọ ní igun mẹrin, òòró ati ìbú ìlẹ̀kùn wọn sì dọ́gba. Kinní kan tí ó dàbí pẹpẹ tí a fi igi ṣe wà níwájú ibi mímọ́. Gíga rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ mẹta (mita 1½), òòró rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji (bíi mita kan), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ meji. Igi ni wọ́n fi ṣe igun rẹ̀, ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ati ara rẹ̀. Ọkunrin náà sọ fún mi pé: “Èyí ni tabili tí ó wà níwájú OLUWA.” Ibi mímọ́ jùlọ, ati ibi mímọ́ ní ìlẹ̀kùn meji meji. Àwọn ìlẹ̀kùn náà ní awẹ́ meji meji. Awẹ́ meji meji tí ó ṣe é ṣí láàrin ni ìlẹ̀kùn kọ̀ọ̀kan ní. Wọ́n gbẹ́ àwòrán igi ọ̀pẹ ati kerubu sí ara ìlẹ̀kùn ibi mímọ́ jùlọ, bí èyí tí wọ́n gbẹ́ sí ara àwọn ògiri. Ìbòrí kan tí a fi pákó ṣe wà níwájú ìloro ní ìta. Àwọn fèrèsé aláṣìítì, tí wọ́n gbẹ́ igi ọ̀pẹ sí lára, wà lára ògiri ìloro náà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji. Lẹ́yìn náà ó mú mi jáde, ó mú mi wọ inú gbọ̀ngàn ti inú lápá ìhà àríwá, ó sì mú mi wọ inú àwọn yàrá tí ó wà níwájú àgbàlá Tẹmpili, ati níwájú ilé tí ó wà ní ìhà àríwá. Òòró ilé tí ó wà ní ìhà àríwá náà jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 50), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ aadọta igbọnwọ (mita 25). Ibùjókòó-òkè meji tí ó kọjú sí ara wọn wà ní àgbékà mẹtẹẹta; wọ́n wà lára ògiri láti nǹkan bíi ogún igbọnwọ sí ara gbọ̀ngàn inú, ati ibi tí ó kọjú sí pèpéle tí ó wà lára gbọ̀ngàn òde. Ọ̀nà kan wà níwájú àwọn yàrá tí ó lọ sinu, ó fẹ̀ ní igbọnwọ mẹ́wàá (mita 5), ó sì gùn ní ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 50), àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ wà ní ìhà àríwá. Àwọn yàrá ti àgbékà kẹta kéré, nítorí ibùjókòó-òkè ti àgbékà kẹta fẹ̀ ju àwọn tí wọ́n wà níwájú àwọn yàrá àgbékà kinni ati ti àgbékà ààrin lọ. Àgbékà mẹta ni àwọn yàrá náà, ọgbọ̀n yàrá ni ó wà lára ògiri ní àjà kọ̀ọ̀kan, wọn kò sì ní òpó bíi ti gbọ̀ngàn ìta, nítorí náà ni wọ́n ṣe sún àwọn yàrá àgbékà òkè kẹta sinu ju ti àwọn yàrá àgbékà kinni ati ti ààrin lọ. Ògiri kan wà ní ìta tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ àwọn yàrá ní apá ti gbọ̀ngàn ìta, ó wà níwájú àwọn yàrá náà, gígùn rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ, (mita 25). Àwọn yàrá ti gbọ̀ngàn ìta gùn ní aadọta igbọnwọ (mita 25), ṣugbọn àwọn tí wọ́n wà níwájú tẹmpili jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 50). Nísàlẹ̀ àwọn yàrá wọnyi, ọ̀nà kan wà ní apá ìlà oòrùn bí eniyan bá ti ń bọ̀ láti ibi gbọ̀ngàn ìta. Bákan náà, àwọn yàrá kan wà ní ìhà gúsù, lára ògiri òòró àgbàlá ti ìta, wọ́n fara kan àgbàlá tẹmpili, ọ̀nà wà níwájú wọn. Wọ́n rí bí àwọn yàrá ti ìhà àríwá, òòró ati ìbú wọn rí bákan náà. Bákan náà ni ẹnu ọ̀nà wọn rí, ati ìlẹ̀kùn wọn. Nísàlẹ̀ àwọn yàrá ìhà gúsù, ọ̀nà kan wà ní apá ìlà oòrùn. Bí eniyan bá wọ àlàfo náà, ògiri kan dábùú rẹ̀ níwájú. Lẹ́yìn náà, ọkunrin náà wí fún mi pé, “Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ ìhà àríwá ati àwọn yàrá ìhà gúsù tí wọ́n kọjú sí àgbàlá ni àwọn yàrá mímọ́. Níbẹ̀ ni àwọn alufaa tí ń rú ẹbọ sí OLUWA yóo ti máa jẹ ẹbọ mímọ́ jùlọ. Níbẹ̀ ni wọn yóo máa kó àwọn ẹbọ mímọ́ jùlọ sí; ati àwọn ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, nítorí ibẹ̀ jẹ́ ibi mímọ́. Nígbà tí àwọn alufaa bá wọ ibi mímọ́, wọn kò gbọdọ̀ jáde sí gbọ̀ngàn ìta láìbọ́ aṣọ tí wọ́n lò sinu yàrá wọnyi, nítorí pé aṣọ mímọ́ ni wọ́n. Wọ́n gbọdọ̀ wọ aṣọ mìíràn kí wọ́n tó súnmọ́ àwọn ohun tí ó jẹ́ ti gbogbo eniyan.” Nígbà tí ó ti parí wíwọn inú Tẹmpili, ó mú mi gba ẹnu ọ̀nà tí ó kọjú sí ìlà oòrùn jáde, ó sì wọn ẹ̀yìn Tẹmpili yíká. Ó wọn apá ìlà oòrùn pẹlu ọ̀pá rẹ̀, ó jẹ́ ẹẹdẹgbẹta (500) igbọnwọ (mita 250), gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó yipada, ó wọn ìhà àríwá, ó jẹ́ ẹẹdẹgbẹta (500) igbọnwọ (mita 250), gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó yipada, ó wọn ìhà gúsù, ó jẹ́ ẹẹdẹgbẹta (500) igbọnwọ (mita 250), gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó yipada, ó wọn apá ìwọ̀ oòrùn, ó jẹ́ ẹẹdẹgbẹta (500) igbọnwọ (mita 250), gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá rẹ̀. Ẹ̀gbẹ́ mẹrẹẹrin ni ó wọ̀n. Tẹmpili náà ní ògiri yíká, òòró rẹ̀ jẹ́ ẹẹdẹgbẹta (500) igbọnwọ (mita 250), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ẹẹdẹgbẹta (500) igbọnwọ (mita 250), èyí ni ó jẹ́ ààlà láàrin ibi mímọ́ ati ibi tí ó jẹ́ ti gbogbo eniyan. Lẹ́yìn náà, ó mú mi wá sí ẹnu ọ̀nà tí ó kọjú sí ìhà ìlà oòrùn. Wò ó! Ìtànṣán ògo Ọlọrun Israẹli yọ láti apá ìlà oòrùn, ìró bíbọ̀ rẹ̀ dàbí ti omi òkun, ìmọ́lẹ̀ ògo rẹ̀ sì tàn sórí ilẹ̀. Ìran tí mo rí yìí dàbí èyí tí mo rí nígbà tí Ọlọrun wá pa ìlú Jerusalẹmu run ati bí ìran tí mo rí létí odò Kebari; mo bá dojúbolẹ̀. Ìtànṣán ògo OLUWA wọ inú Tẹmpili láti ẹnu ọ̀nà tí ó kọjú sí ìlà oòrùn. Ẹ̀mí bá gbé mi dìde, ó mú mi wá sinu gbọ̀ngàn inú; ìtànṣán ògo OLUWA sì kún inú Tẹmpili náà. Bí ọkunrin náà ti dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, mo gbọ́ tí ẹnìkan ń bá mi sọ̀rọ̀ láti inú Tẹmpili, ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, ààyè ìtẹ́ mi nìyí, ati ibi ìgbẹ́sẹ̀lé mi. Níbẹ̀ ni n óo máa gbé láàrin àwọn eniyan Israẹli títí lae. Ilé Israẹli tabi àwọn ọba wọn kò ní fi àgbèrè ẹ̀sìn wọn, ati òkú àwọn ọba wọn ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mọ́. Wọn kò ní tẹ́ pẹpẹ wọn sí ẹ̀gbẹ́ tèmi mọ́, tabi kí wọn gbé òpó ìlẹ̀kùn wọn sí ẹ̀gbẹ́ tèmi; tí ó fi jẹ́ pé ògiri kan ni yóo wà láàrin èmi pẹlu wọn. Wọ́n ti fi ìwà ìríra wọn ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́, nítorí náà ni mo ṣe fi ibinu pa wọ́n run. Kí wọ́n pa ìwà ìbọ̀rìṣà wọn tì, kí wọ́n sì gbé òkú àwọn ọba wọn jìnnà sí mi, n óo sì máa gbé ààrin wọn títí lae. “Ìwọ ọmọ eniyan, ṣe àpèjúwe Tẹmpili yìí, sọ bí ó ti rí ati àwòrán kíkọ́ rẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí ojú ẹ̀ṣẹ̀ wọn lè tì wọ́n. Bí ojú ohun tí wọ́n ṣe bá tì wọ́n, ṣe àlàyé Tẹmpili náà, bí o ti rí i, ẹnu ọ̀nà àbájáde ati àbáwọlé rẹ̀. Sọ bí o ti rí i fún wọn, sì fi àwọn àṣẹ ati òfin rẹ̀ hàn wọ́n. Kọ wọ́n sílẹ̀ lójú wọn, kí wọ́n lè máa pa àwọn àṣẹ ati òfin rẹ̀ mọ́. Òfin Tẹmpili nìyí, gbogbo agbègbè tí ó yí orí òkè ńlá tí ó wà ká gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ jùlọ.” Bí ìwọ̀n pẹpẹ náà ti rí nìyí; irú ọ̀pá kan náà tí ó jẹ́ igbọnwọ kan ati ìbú àtẹ́lẹwọ́ (ìdajì mita kan) kan ni ó fi wọ̀n ọ́n. Pèpéle pẹpẹ náà yóo ga ní igbọnwọ kan, yóo fẹ̀ ní igbọnwọ kan. Etí rẹ̀ yíká fẹ̀ ní ìka kan (idamẹrin mita kan). Gíga pẹpẹ láti pèpéle tí ó wà nílẹ̀ títí dé ìtẹ́lẹ̀ ìsàlẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji (mita kan). Ìbú rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan (ìdajì mita kan). Láti ìtẹ́lẹ̀ kékeré títí dé ìtẹ́lẹ̀ ńlá jẹ́ igbọnwọ mẹrin (mita meji). Ibú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan (idaji mita kan). Orí pẹpẹ náà ga ní igbọnwọ mẹrin (mita meji). Ìwo mẹrin wà lára rẹ̀, wọ́n gùn ní igbọnwọ kọ̀ọ̀kan (ìdajì mita kan). Orí pẹpẹ náà ní igun mẹrin, òòró rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ mejila (mita mẹfa) ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mejila (mita mẹfa). Ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ náà ní igun mẹrin, ó ga ní igbọnwọ mẹrinla (mita meje), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹrinla (mita meje). Etí rẹ̀ yíká jẹ́ ìdajì igbọnwọ (idamẹrin mita), pèpéle rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan yíká (ìdajì mita kan). Àtẹ̀gùn pẹpẹ náà kọjú sí apá ìlà oòrùn. Ọkunrin náà wí fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Àwọn òfin pẹpẹ nìwọ̀nyí, ní ọjọ́ tí a bá gbé e kalẹ̀ láti máa rú ẹbọ sísun lórí rẹ̀ ati láti máa ta ẹ̀jẹ̀ sí i lára, ẹ óo fún àwọn alufaa, ọmọ Lefi, láti inú ìran Sadoku, tí wọn ń rú ẹbọ sí mi, ní akọ mààlúù kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ óo fi sí ara ìwo pẹpẹ ati igun mẹrẹẹrin pèpéle rẹ̀, ati ara etí rẹ̀ yíká, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe wẹ pẹpẹ náà mọ́; bẹ́ẹ̀ ni ètò ìwẹ̀nùmọ́ pẹpẹ lọ. Ẹ óo mú akọ mààlúù ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀; ẹ óo sun ún ní ibi tí a yàn lára ilẹ̀ Tẹmpili ní ìta ibi mímọ́. Ní ọjọ́ keji ẹ óo fi òbúkọ tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ẹ ya pẹpẹ náà sí mímọ́ bí ẹ ti fi ẹbọ akọ mààlúù yà á sí mímọ́. Bí ẹ bá ti yà á sí mímọ́ tán, ẹ óo mú akọ mààlúù tí kò ní àbààwọ́n ati àgbò tí kò ní àbààwọ́n láti inú agbo ẹran, ẹ óo fi rú ẹbọ. Ẹ óo kó wọn wá siwaju OLUWA, alufaa yóo wọ́n iyọ̀ lé wọn lórí, yóo sì fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí OLUWA. Lojoojumọ, fún ọjọ́ meje, ẹ óo máa mú ewúrẹ́ kọ̀ọ̀kan ati akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbààwọ́n láti inú agbo ẹran, ẹ óo máa fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Fún ọjọ́ meje ni ẹ óo fi máa rú ẹbọ ìwẹ̀nùmọ́ fún pẹpẹ náà tí ẹ óo sì máa yà á sí mímọ́; bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe yà á sọ́tọ̀ fún lílò. Tí ètò àwọn ọjọ́ wọnyi bá ti parí, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kẹjọ, àwọn alufaa yóo máa rú ẹbọ sísun yín ati ẹbọ alaafia yín lórí pẹpẹ náà, n óo sì máa tẹ́wọ́gbà wọ́n. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ” Lẹ́yìn náà ó mú mi wá sí ẹnu ọ̀nà ìta ibi mímọ́ tí ó kọjú sí ìlà oòrùn, ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà náà wà ní títì. OLUWA wí fún mi pé, “Ìlẹ̀kùn yìí yóo máa wà ní títì ni, wọn kò gbọdọ̀ ṣí i; ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ gba ibẹ̀ wọlé, nítorí èmi OLUWA, Ọlọrun Israẹli, ti gba ibẹ̀ wọlé. Nítorí náà, títì ni yóo máa wà. Ọba nìkan ni ó lè jókòó níbẹ̀ láti jẹun níwájú OLUWA. Yóo gba ẹnu ọ̀nà ìloro wọlé, ibẹ̀ náà ni yóo sì gbà jáde.” Lẹ́yìn náà, ọkunrin náà mú mi gba ẹnu ọ̀nà ìhà àríwá wá siwaju tẹmpili; mo sì rí i tí ìtànṣán ògo OLUWA kún inú tẹmpili, mo bá dojúbolẹ̀. OLUWA bá sọ fún mi pé: “Ìwọ ọmọ eniyan, ṣe akiyesi dáradára, ya ojú rẹ, kí o sì fi etí sílẹ̀ kí o gbọ́ gbogbo ohun tí n óo sọ fún ọ nípa àṣẹ ati àwọn òfin tí ó jẹ mọ́ tẹmpili OLUWA. Ṣe akiyesi àwọn eniyan tí a lè gbà láàyè kí wọ́n wọ inú tẹmpili ati àwọn tí kò gbọdọ̀ wọlé. “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, àwọn olóríkunkun, pé OLUWA Ọlọrun ní, ‘Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ dáwọ́ àwọn nǹkan ìríra tí ẹ̀ ń ṣe dúró. Nígbà tí ẹ̀ ń gbà fún àwọn àlejò, tí a kò kọ nílà abẹ́, ati ti ọkàn, láti máa wọ ibi mímọ́ mi nígbà tí ẹ bá ń fi ọ̀rá ati ẹ̀jẹ̀ rú ẹbọ sí mi, ibi mímọ́ mi ni ẹ̀ ń sọ di aláìmọ́. Ẹ ti fi àwọn ohun ìríra yín ba majẹmu mi jẹ́. Ẹ kò tọ́jú àwọn ohun mímọ́ mi, àwọn àlejò ni ẹ ti fi ṣe alákòóso níbẹ̀. “ ‘Nítorí náà, ẹni tí kò bá kọlà ọkàn ati ti ara ninu àwọn àlejò tí wọn ń gbé ààrin àwọn ọmọ Israẹli kò gbọdọ̀ wọ ibi mímọ́ mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ” OLUWA ní, “Ṣugbọn àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n pada lẹ́yìn mi, tí wọ́n ṣáko lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn oriṣa wọn nígbà tí Israẹli ṣáko lọ, yóo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Wọ́n lè jẹ́ iranṣẹ ninu ibi mímọ́ mi, wọ́n lè máa ṣe alákòóso àwọn ẹnu ọ̀nà tẹmpili, wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ ninu tẹmpili, wọ́n lè máa pa ẹran ẹbọ sísun ati ẹran ẹbọ àwọn eniyan, wọ́n lè máa ṣe iranṣẹ fún àwọn eniyan. Nítorí pé wọ́n ti jẹ́ iranṣẹ fún wọn níwájú àwọn oriṣa, wọ́n sì di ohun ìkọsẹ̀ tí ó mú ilé Israẹli dẹ́ṣẹ̀, nítorí náà, mo ti búra nítorí wọn pé wọ́n gbọdọ̀ jìyà. Wọn kò gbọdọ̀ dé ibi pẹpẹ mi láti ṣe iṣẹ́ alufaa, wọn kò gbọdọ̀ súnmọ́ àwọn ohun mímọ́ mi ati àwọn ohun mímọ́ jùlọ; ojú yóo tì wọ́n nítorí ohun ìríra tí wọ́n ṣe. Sibẹsibẹ, n óo yàn wọ́n láti máa tọ́jú tẹmpili ati láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó yẹ ní ṣíṣe ninu rẹ̀. “Ṣugbọn àwọn alufaa ọmọ Lefi láti ìran Sadoku, tí wọn ń tọ́jú ibi mímọ́ mi nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ṣáko lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, àwọn ni yóo máa lọ sí ibi pẹpẹ mi láti rúbọ sí mi. Àwọn ni wọn óo máa fi ọ̀rá ati ẹ̀jẹ̀ rú ẹbọ sí mi. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Àwọn ni wọn óo máa wọ ibi mímọ́ mi, wọn óo máa lọ sí ibi tabili mi, tí wọn óo máa ṣiṣẹ́ iranṣẹ, wọn óo sì máa pa àṣẹ mi mọ́. Bí wọ́n bá ti dé àwọn ẹnu ọ̀nà gbọ̀ngàn inú, wọn yóo wọ aṣọ funfun. Wọn kò ní wọ ohunkohun tí a fi irun aguntan hun nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ iranṣẹ lẹ́nu ọ̀nà ati ninu gbọ̀ngàn inú. Wọn yóo wé lawani tí a fi aṣọ funfun rán, wọn yóo sì wọ ṣòkòtò aṣọ funfun. Wọn kò gbọdọ̀ fi ohunkohun tí ń mú kí ooru mú eniyan di ara wọn ní àmùrè. Nígbà tí wọ́n bá fẹ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan ní gbọ̀ngàn ìta, wọn yóo bọ́ aṣọ tí wọ́n wọ̀ nígbà tí wọn ń ṣiṣẹ́ iranṣẹ sí àwọn yàrá mímọ́. Wọn yóo wọ aṣọ mìíràn kí wọn má baà sọ àwọn eniyan náà di mímọ́ nítorí ẹ̀wù wọn. “Wọn kò gbọdọ̀ fá irun orí wọn tabi kí wọn jẹ́ kí oko irun wọn gùn, wọn yóo máa gé díẹ̀díẹ̀ lára irun orí wọn ni. Kò sí alufaa kan tí ó gbọdọ̀ mu ọtí waini nígbà tí ó bá wọ gbọ̀ngàn inú. Wọn kò gbọdọ̀ fẹ́ opó tabi obinrin tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀, àfi wundia tí kò tíì mọ ọkunrin láàrin àwọn eniyan Israẹli tabi opó tí ó jẹ́ aya alufaa. “Wọ́n gbọdọ̀ kọ́ àwọn eniyan mi láti mọ ìyàtọ̀ láàrin àwọn nǹkan mímọ́ tí a yà sọ́tọ̀ ati àwọn nǹkan lásán. Wọ́n sì gbọdọ̀ kọ́ wọn láti mọ ìyàtọ̀ láàrin nǹkan tí kò mọ́ ati àwọn nǹkan mímọ́. Bí àríyànjiyàn bá bẹ́ sílẹ̀, àwọn ni wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ onídàájọ́, wọ́n sì gbọdọ̀ ṣe ìdájọ́ gẹ́gẹ́ bí èmi gan-an yóo ti ṣe é. Wọ́n gbọdọ̀ pa àwọn òfin ati ìlànà mi mọ́ lákòókò gbogbo àṣàyàn àjọ̀dún wọn, wọ́n sì gbọdọ̀ ya ọjọ́ ìsinmi mi sí mímọ́. “Wọn kò gbọdọ̀ sọ ara wọn di aláìmọ́ nípa sísúnmọ́ òkú, ṣugbọn wọ́n lè sọ ara wọn di aláìmọ́ bí ó bá jẹ́ pé òkú náà jẹ́ ti baba wọn tabi ìyá wọn tabi ti ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin tabi ti arakunrin wọn tí kò tíì gbeyawo tabi arabinrin wọn tí kò tíì wọ ilé ọkọ. Lẹ́yìn tí alufaa bá di aláìmọ́, yóo dúró fún ọjọ́ meje, lẹ́yìn náà yóo di mímọ́. Ní ọjọ́ tí ó bá lọ sí ibi mímọ́, tí ó bá lọ sinu gbọ̀ngàn inú láti ṣiṣẹ́ iranṣẹ ní ibi mímọ́, ó gbọdọ̀ rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “Wọn kò ní ní ilẹ̀ ìní nítorí èmi ni ìní wọn, ẹ kò ní pín ilẹ̀ fún wọn ní Israẹli, èmi ni ìpín wọn. Àwọn ni wọn óo máa jẹ ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, àwọn ni wọ́n ni gbogbo ohun tí a bá yà sọ́tọ̀ ní Israẹli. Gbogbo àkọ́so oniruuru èso ati oniruuru ọrẹ gbọdọ̀ jẹ́ ti àwọn alufaa. Ẹ sì gbọdọ̀ fún àwọn alufaa mi ní àkọ́pò ìyẹ̀fun yín kí ibukun lè wà ninu ilé yín. Àwọn alufaa kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó bá kú fúnrarẹ̀ tabi tí ẹranko burúkú bá pa, kì báà jẹ́ ẹyẹ tabi ẹranko. “Nígbà tí ẹ bá pín ilẹ̀ náà fún àwọn eniyan, ẹ ya ilẹ̀ kan sọ́tọ̀ fún OLUWA, tí yóo jẹ́ ilẹ̀ mímọ́. Gígùn rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ, ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan (20,000) igbọnwọ. Ilẹ̀ mímọ́ ni gbogbo ilẹ̀ náà yóo jẹ́. Ẹ óo fi ààyè sílẹ̀ ninu ilẹ̀ yìí fún Tẹmpili mímọ́, ìbú ati òòró rẹ̀ yóo jẹ́ ẹẹdẹgbẹta (500) igbọnwọ, ẹ óo sì tún fi aadọta igbọnwọ ilẹ̀ sílẹ̀ yí i ká. Lára ilẹ̀ mímọ́ náà, ẹ óo wọn apá kan tí òòró rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), tí ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 10), níbẹ̀ ni ilé mímọ́ yóo wà, yóo jẹ́ ibi mímọ́ jùlọ. Yóo jẹ́ ibi mímọ́ lára ilẹ̀ náà, yóo wà fún àwọn alufaa, tí ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ní ibi mímọ́, tí wọ́n sì ń dúró níwájú OLUWA láti ṣe iṣẹ́ iranṣẹ. Ibẹ̀ ni wọn yóo kọ́ ilé wọn sí, ibẹ̀ ni yóo sì jẹ́ ilẹ̀ mímọ́ fún ibi mímọ́ mi. Ẹ wọn ibòmíràn tí òòró rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), tí ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 10). Ibẹ̀ ni yóo wà fún àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń ṣiṣẹ́ ninu tẹmpili, ibẹ̀ ni wọn óo máa gbé. “Lára ilẹ̀ mímọ́ náà, ẹ óo ya apá kan sọ́tọ̀ tí òòró rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), tí ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ẹẹdẹgbaata (5,000) igbọnwọ (kilomita 2½), ilẹ̀ yìí yóo wà fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli. “Ọba ni yóo ni ilẹ̀ tí ó yí ilẹ̀ mímọ́ náà ká nì ẹ̀gbẹ́ kinni keji, ati àwọn ilẹ̀ tí ó wà ninu ìlú náà, ní ìwọ̀ oòrùn ati ìlà oòrùn, yóo gùn tó ilẹ̀ ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli, yóo bẹ̀rẹ̀ ní òpin ìwọ̀ oòrùn yóo sì dé òpin ìlà oòrùn ilẹ̀ náà. Yóo jẹ́ ìpín ti ọba ní Israẹli. Àwọn ọba kò gbọdọ̀ ni àwọn eniyan mi lára mọ́, wọ́n gbọdọ̀ fi ilẹ̀ yòókù sílẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn.” OLUWA Ọlọrun ní, “Ó tó gẹ́ẹ́, ẹ̀yin ọba Israẹli, ẹ má hùwà ipá ati ìninilára mọ́, ẹ máa hùwà ẹ̀tọ́ ati òdodo, ẹ má lé àwọn eniyan mi jáde mọ́. “Òṣùnwọ̀n eefa ati ti bati tí ó péye ni kí ẹ máa lò. “Òṣùnwọ̀n eefa ati òṣùnwọ̀n bati náà gbọdọ̀ jẹ́ ìwọ̀n kan náà, eefa ati bati yín gbọdọ̀ jẹ́ ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n homeri kan. Òṣùnwọ̀n homeri ni ó gbọdọ̀ jẹ́ òṣùnwọ̀n tí ẹ óo máa fi ṣiṣẹ́. “Ogún òṣùnwọ̀n gera ni yóo wà ninu òṣùnwọ̀n ṣekeli kan. Ṣekeli marun-un gbọdọ̀ pé ṣekeli marun-un. Ṣekeli mẹ́wàá sì gbọdọ̀ pé ṣekeli mẹ́wàá; òṣùnwọ̀n mina sì gbọdọ̀ pé aadọta ṣekeli. “Ohun tí ẹ óo máa fi rúbọ sí OLUWA nìwọ̀nyí: ìdámẹ́fà òṣùnwọ̀n eefa kan ninu òṣùnwọ̀n homeri ọkà yín kọ̀ọ̀kan, ati ìdámẹ́fà òṣùnwọ̀n eefa kan ninu òṣùnwọ̀n homeri alikama yín kọ̀ọ̀kan. Ìwọ̀n òróró gbọdọ̀ péye gẹ́gẹ́ bí ìlànà; ìdámẹ́wàá ìwọ̀n bati mẹ́wàá ni òṣùnwọ̀n bati kan ninu òṣùnwọ̀n kori kọ̀ọ̀kan òṣùnwọ̀n kori gẹ́gẹ́ bíi ti homeri. Ẹ níláti ya aguntan kọ̀ọ̀kan sọ́tọ̀ ninu agbo ẹran kọ̀ọ̀kan tí ó tó igba ẹran, ninu àwọn agbo ẹran ìdílé Israẹli. Ẹ yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ẹbọ ohun jíjẹ, ati ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia, kí wọ́n lè ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “Àwọn ọmọ Israẹli gbọdọ̀ kó àwọn nǹkan ìrúbọ náà fún àwọn ọba Israẹli. Ọba ni ó gbọdọ̀ máa pèsè ẹbọ sísun, ẹbọ ohun jíjẹ, ati ẹbọ ohun mímu ní gbogbo ọjọ́ àjọ̀dún, ati àwọn ọjọ́ oṣù tuntun, àwọn ọjọ́ ìsinmi ati àwọn ọjọ́ àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli. Òun ni yóo máa pèsè ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia láti ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli.” OLUWA Ọlọrun ní, “Ní ọjọ́ kinni oṣù kinni, ẹ pa ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan tí kò ní àbààwọ́n, kí ẹ fi ṣe ìwẹ̀nùmọ́ ibi mímọ́. Alufaa yóo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, yóo fi sí ara òpó ìlẹ̀kùn tẹmpili, ati orígun mẹrẹẹrin pẹpẹ ati òpó ìlẹ̀kùn àbáwọlé gbọ̀ngàn ààrin ilé. Bákan náà ni ẹ gbọdọ̀ ṣe ní ọjọ́ keje oṣù láti ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀; kí ẹ lè ṣe ètùtù fún tẹmpili. “Ní ọjọ́ kẹrinla oṣù kinni, ẹ gbọdọ̀ ṣe ọdún Àjọ Ìrékọjá, burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ni ẹ óo máa jẹ fún ọjọ́ meje. Ní ọjọ́ náà ọba yóo pa ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀ ati fún gbogbo àwọn ará ìlú. Fún ọjọ́ meje tí ẹ óo fi ṣe àjọ̀dún yìí, yóo mú ọ̀dọ́ akọ mààlúù meje ati àgbò meje tí kò ní àbààwọ́n wá fún ẹbọ sísun, ati òbúkọ kọ̀ọ̀kan fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Fún ẹbọ ohun jíjẹ yóo pèsè òṣùnwọ̀n eefa ìyẹ̀fun kọ̀ọ̀kan fún akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan, òṣùnwọ̀n eefa ìyẹ̀fun kọ̀ọ̀kan fún àgbò kọ̀ọ̀kan ati òṣùnwọ̀n hini òróró kọ̀ọ̀kan fún òṣùnwọ̀n eefa ìyẹ̀fun kọ̀ọ̀kan. “Ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù keje, tíí ṣe ọjọ́ keje àjọ̀dún náà, yóo pèsè irú ẹbọ kan náà fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati òróró.” OLUWA Ọlọrun ní, “Ẹnu ọ̀nà àgbàlá inú tí ó kọjú sí ìlà oòrùn gbọdọ̀ wà ní títì fún ọjọ́ mẹfa tí a fi ń ṣiṣẹ́. Ṣugbọn ẹ máa ṣí i ní ọjọ́ ìsinmi ati ọjọ́ oṣù tuntun. Yàrá àbáwọlé ẹnu ọ̀nà yìí ni ọba yóo gbà wọlé, yóo sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó ẹnu ọ̀nà. Àwọn alufaa yóo rú ẹbọ sísun ati ti alaafia rẹ̀. Ọba yóo jọ́sìn ní ẹnu ọ̀nà àbájáde, yóo sì jáde; ṣugbọn wọn kò ní ti ìlẹ̀kùn náà títí di ìrọ̀lẹ́. Àwọn eniyan yóo jọ́sìn ní ẹnu ọ̀nà àbáwọlé níwájú OLUWA ní ọjọ́ ìsinmi ati ní ọjọ́ ìbẹ̀rẹ̀ oṣù. Ọ̀dọ́ aguntan mẹfa tí kò lábàwọ́n ati àgbò kan tí kò lábàwọ́n ni ọba yóo fi rú ẹbọ ọrẹ sísun sí OLUWA ní ọjọ́ ìsinmi. Ẹbọ ọkà pẹlu àgbò yóo jẹ́ ìwọ̀n eefa kan. Ìwọ̀n ọkà pẹlu iye ọ̀dọ́ aguntan tí ó bá lágbára ni yóo fi rú ẹbọ ọkà pẹlu ọ̀dọ́ aguntan. Ṣugbọn ó gbọdọ̀ fi òróró hini kọ̀ọ̀kan ti eefa ìyẹ̀fun kọ̀ọ̀kan. Ní ọjọ́ kinni oṣù, yóo fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan ati ọ̀dọ́ aguntan mẹfa ati àgbò kan tí kò lábàwọ́n rúbọ. Fún ẹbọ ohun jíjẹ, yóo tọ́jú ìwọ̀n eefa ọkà kan fún akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan, ati eefa ọkà kan fún àgbò kọ̀ọ̀kan ati ìwọ̀n ọkà tí ó bá ti lágbára fún àwọn àgbò, yóo fi hini òróró kọ̀ọ̀kan ti eefa ọkà kọ̀ọ̀kan. Ẹnu ọ̀nà àbáwọlé náà ni ọba yóo gbà wọlé, ibẹ̀ náà ni yóo sì gbà jáde. “Ṣugbọn nígbà tí àwọn ará ìlú bá wá siwaju OLUWA ní àkókò àjọ̀dún, ẹni tí ó bá gba ẹnu ọ̀nà apá àríwá wọlé, ẹnu ọ̀nà gúsù ni ó gbọdọ̀ gbà jáde, ẹni tí ó bá sì gba ẹnu ọ̀nà gúsù wọlé, ẹnu ọ̀nà àríwá ni ó gbọdọ̀ gbà jáde. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ gba ẹnu ọ̀nà tó gbà wọlé jáde. Tààrà ni kí olukuluku máa lọ títí yóo fi jáde. Ọba yóo bá wọn wọlé nígbà tí wọ́n bá wọlé, nígbà tí wọ́n bá sì jáde, yóo bá wọn jáde. Ní ọjọ́ àsè ati ìgbà àjọ̀dún, ìwọ̀n eefa ọkà kan ni wọn óo fi rúbọ pẹlu ọ̀dọ́ mààlúù kan, ìwọ̀n eefa ọkà kan pẹlu àgbò kan, ati ìwọ̀n eefa ọkà tí eniyan bá lágbára pẹlu ọ̀dọ́ aguntan, ṣugbọn ó gbọdọ̀ fi ìwọ̀n òróró hini kọ̀ọ̀kan ti ìwọ̀n eefa ọkà kọ̀ọ̀kan. “Nígbà tí ọba bá pèsè ẹbọ ọrẹ àtinúwá, kì báà ṣe ẹbọ sísun, tabi ẹbọ alaafia, ni ọrẹ àtinúwá fún OLUWA tí ó pèsè, wọn yóo ṣí ẹnubodè tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn fún un, yóo sì rú ẹbọ sísun tabi ẹbọ alaafia rẹ̀ bíi ti ọjọ́ ìsinmi. Lẹ́yìn náà yóo jáde, wọn óo sì ti ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà náà.” OLUWA ní, “Yóo máa pèsè ọ̀dọ́ aguntan ọlọ́dún kan tí kò lábàwọ́n fún ẹbọ sísun sí OLUWA lojoojumọ. Láràárọ̀ ni yóo máa pèsè rẹ̀. Ẹbọ ohun jíjẹ tí yóo máa pèsè pẹlu rẹ̀ láràárọ̀ ni: ìdámẹ́fà eefa ìyẹ̀fun ati ìdámẹ́ta hini òróró tí wọn yóo fi máa po ìyẹ̀fun náà fún ẹbọ ohun jíjẹ fún OLUWA. Èyí ni yóo jẹ́ ìlànà fún ẹbọ sísun ìgbà gbogbo. Bẹ́ẹ̀ ni wọn óo ṣe máa pèsè aguntan ati ẹbọ ohun jíjẹ ati òróró láràárọ̀, fún ẹbọ ọrẹ sísun ìgbà gbogbo.” OLUWA Ọlọrun ní, “Bí ọba bá fún ọ̀kankan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ ní ẹ̀bùn lára ilẹ̀ rẹ̀, ilẹ̀ náà di ti àwọn ọmọ rẹ̀, ó di ohun ìní wọn tí wọ́n jogún. Ṣugbọn bí ó bá fún ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ ní ẹ̀bùn lára ilẹ̀ rẹ̀, ilẹ̀ náà di tirẹ̀ títí di ọjọ́ tí yóo gba òmìnira; láti ọjọ́ náà ni ilẹ̀ náà yóo ti pada di ti ọba. Àwọn ọmọ rẹ̀ nìkan ni wọ́n lè jogún ilẹ̀ rẹ̀ títí lae. Ọba kò gbọdọ̀ gbà ninu ilẹ̀ àwọn ará ìlú láti ni wọ́n lára; ninu ilẹ̀ tirẹ̀ ni kí ó ti pín ogún fún àwọn ọmọ rẹ̀. Kí ẹnikẹ́ni má baà gba ilẹ̀ ọ̀kankan ninu àwọn eniyan mi kúrò lọ́wọ́ wọn.” Ọkunrin náà bá mú mi gba ọ̀nà tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ìlẹ̀kùn, ó bá mú mi lọ sí ibi àwọn yàrá tí ó wà ní apá àríwá ibi mímọ́ náà, tí ó jẹ́ ti àwọn alufaa, mo sì rí ibìkan níbẹ̀ tí ó wà ní ìpẹ̀kun ní apá ìwọ̀ oòrùn. OLUWA wá sọ fún mi pé, “Ní ibí yìí ni àwọn alufaa yóo ti máa se ẹran ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi ati ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Ibẹ̀ ni wọn yóo sì ti máa ṣe burẹdi fún ẹbọ ohun jíjẹ, kí wọn má baà kó wọn jáde wá sí gbọ̀ngàn tí ó wà ní ìta, kí wọn má baà fi ohun mímọ́ kó bá àwọn eniyan.” Ọkunrin náà bá mú mi wá sí ibi gbọ̀ngàn tí ó wà ní ìta, ó mú mi yíká gbogbo igun mẹrẹẹrin gbọ̀ngàn náà, gbọ̀ngàn kéékèèké kọ̀ọ̀kan sì wà ní igun kọ̀ọ̀kan. Ní igun mẹrẹẹrin ni àwọn gbọ̀ngàn kéékèèké yìí wà. Ó gùn ní ogoji igbọnwọ (mita 20), ó sì fẹ̀ ní ọgbọ̀n igbọnwọ (mita 15) àwọn mẹrẹẹrin sì rí bákan náà. Wọ́n fi òkúta kọ́ igun mẹrẹẹrin, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yípo. Wọ́n sì kọ́ ibi ìdáná wọn mọ́ ara ògiri. Nígbà náà ni ó wí fún mi pé, “Àwọn ilé ìdáná níbi tí àwọn alufaa tí óo wà níbi pẹpẹ yóo ti máa se ẹran ẹbọ àwọn eniyan mi nìyí.” Ọkunrin náà bá mú mi pada wá sí ẹnu ọ̀nà Tẹmpili, mo sì rí i tí omi kan ń sun láti abẹ́ ìlẹ̀kùn àbájáde ó ń ṣàn lọ sí ìhà ìlà oòrùn, ìhà ìlà oòrùn ni tẹmpili kọjú sí. Omi náà ń ṣàn láti apá gúsù ibi ìlẹ̀kùn àbájáde tí ó wà ni ìhà gúsù pẹpẹ ìrúbọ. Lẹ́yìn náà ó mú mi gba ẹnu ọ̀nà ìhà àríwá jáde, ó sì mú mi yípo ní ìta títí tí mo fi dé ẹnu ọ̀nà àbájáde tí ó kọjú sí ìlà oòrùn. Odò kékeré kan ń ṣàn jáde láti ìhà gúsù. Ọkunrin náà lọ sí apá ìhà ìlà oòrùn, ó mú okùn ìwọ̀n kan lọ́wọ́. Ó fi wọn ẹgbẹrun igbọnwọ, (mita 450). Ó sì mú mi la odò kan tí ó mù mí dé kókósẹ̀ kọjá. Ó tún wọn ẹgbẹrun igbọnwọ (mita 450) mìíràn sí ìsàlẹ̀, ó sì mú mi la odò náà kọjá: odò yìí sì mù mí dé orúnkún. Ọkunrin náà tún wọn ẹgbẹrun igbọnwọ (mita 450) mìíràn sí ìsàlẹ̀, ó tún mú mi la odò náà kọjá: ó sì mù mí dé ìbàdí. Nígbà tí ó yá, ó tún wọn ẹgbẹrun igbọnwọ (mita 450), mìíràn sí ìsàlẹ̀, odò náà jìn ju ohun tí mo lè là kọjá lọ, nítorí pé ó ti kún sí i, ó jìn tó ohun tí eniyan lè lúwẹ̀ẹ́ ninu rẹ̀. Ó kọjá ohun tí eniyan lè là kọjá. Ọkunrin náà bá sọ fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, ṣé o rí nǹkan?” Nígbà náà ni ó mú mi gba etí odò náà pada. Bí mo ṣe ń pada bọ̀, mo rí ọpọlọpọ igi ní bèbè kinni keji odò náà. Ó ní, “Omi yìí ń ṣàn lọ sí Araba, ní ìhà ìlà oòrùn, nígbà tí ó bá sì ṣàn wọ inú òkun, omi inú òkun, yóo di omi tí ó mọ́ gaara. Ọpọlọpọ ohun ẹlẹ́mìí yóo wà ní ibikíbi tí omi náà bá ti ṣàn kọjá. Ẹja yóo pọ̀ ninu rẹ̀; nítorí pé omi yìí ṣàn lọ sí inú òkun, omi tí ó wà níbẹ̀ yóo di mímọ́ gaara, ohunkohun tí ó bá sì wà ní ibi tí odò yìí bá ti ṣàn kọjá yóo yè. Àwọn apẹja yóo dúró létí òkun láti Engedi títí dé Enegilaimu, ibẹ̀ yóo di ibi tí wọn yóo ti máa na àwọ̀n wọn sá sí. Oríṣìíríṣìí ẹja ni yóo wà níbẹ̀ bí ẹja inú Òkun Ńlá. Ṣugbọn ibi ẹrọ̀fọ̀ ati àbàtà rẹ̀ kò ní di mímọ́ gaara, iyọ̀ ni yóo wà níbẹ̀. Oríṣìíríṣìí igi eléso yóo hù ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji odò náà: ewé àwọn igi náà kò ní rọ, bẹ́ẹ̀ ni èso wọn kò ní tán. Lóṣooṣù ni wọn yóo máa so èso tuntun nítorí pé láti inú tẹmpili ni omi rẹ̀ yóo ti máa sun jáde wá. Èso wọn yóo wà fún jíjẹ, ewé wọn yóo sì wà fún ìwòsàn.” OLUWA Ọlọrun ní, “Èyí ni yóo jẹ́ ààlà tí ẹ óo fi pín ilẹ̀ láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli mejeejila. Josẹfu yóo ní ìpín meji; ọgbọọgba ni ẹ sì gbọdọ̀ pín in. Mo ti búra pé n óo fún àwọn baba yín, ilẹ̀ náà yóo sì di ohun ìní yín. “Bí ààlà ilẹ̀ náà yóo ti lọ nìyí: ní apá àríwá, ilẹ̀ náà yóo bẹ̀rẹ̀ láti Òkun Ńlá, yóo gba Etiloni títí dé ẹnubodè Hamati, títí dé ẹnu ibodè Sedadi, àwọn ìlú Berota, Sibiraimu (tí ó wà ní ààlà Damasku ati Hamati), títí dé Haseri Hatikoni, tí ó wà ní ààlà Haurani. Ààlà ilẹ̀ náà yóo bẹ̀rẹ̀ láti ibi òkun títí dé Hasari Enọni, tí ó wà ní ìhà àríwá ààlà Damasku, ààlà ti Hamati yóo wà ní apá àríwá. Èyí ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ náà ní apá ìhà àríwá. “Ní apá ìhà ìlà oòrùn, ààlà náà yóo lọ láti Hasari Enọni tí ó wà láàrin Haurani ati Damasku, ní ẹ̀gbẹ́ odò Jọdani tí ó wà láàrin Gileadi ati ilẹ̀ Israẹli, títí dé òkun tí ó wà ní ìlà oòrùn, yóo sì lọ títí dé Tamari. Èyí ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ náà ní apá ìlà oòrùn. “Ní ìhà gúsù, ilẹ̀ yín yóo lọ láti Tamari dé àwọn odò Meriba Kadeṣi, títí yóo fi kan odò Ijipti títí lọ dé Òkun-ńlá. Èyí ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ náà ní apá ìhà gúsù. “Ní ìwọ̀ oòrùn, Òkun Ńlá ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ yín, yóo lọ títí dé òdìkejì ẹnu ọ̀nà Hamati. Èyí ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ náà ní apá ìwọ̀ oòrùn. “Báyìí ni ẹ óo ṣe pín ilẹ̀ náà láàrin ara yín, gẹ́gẹ́ bí iye ẹ̀yà Israẹli. Ẹ óo pín in fún ara yín ati fún àwọn àlejò tí wọn ń gbé ààrin yín, tí wọ́n sì ti bímọ sí ààrin yín. Ẹ óo kà wọ́n sí ọmọ onílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Ẹ óo pín ilẹ̀ fún àwọn náà. Ààrin ẹ̀yà tí àjèjì náà bá ń gbé ni kí ẹ ti pín ilẹ̀ ìní tirẹ̀ fún un. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” Orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli nìwọ̀nyí: Ààlà ilẹ̀ náà ní ìhà àríwá bẹ̀rẹ̀ láti etíkun, ó lọ ní apá ọ̀nà Hẹtiloni dé àbáwọ Hamati títí dé Hasari Enọni, tí ó wà ní ààlà Damasku, ní òdìkejì Hamati. Ó lọ láti apá ìlà oòrùn títí dé apá ìwọ̀ oòrùn: Ìpín ti Dani yóo jẹ́ ìpín kan. Ìpín ti Aṣeri yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Dani, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn. Ìpín ti Nafutali yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Aṣeri, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn. Ìpín ti Manase yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Nafutali, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn, Ìpín ti Efuraimu yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Manase, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn. Ìpín ti Reubẹni yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Efuraimu, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn. Ìpín ti Juda yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìpín ti Reubẹni, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn. Lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìpín ti Juda ni ilẹ̀ tí ẹ óo yà sọ́tọ̀ fún OLUWA yóo wà. Ìbú rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12.5), òòró rẹ̀ yóo rí bákan náà pẹlu ti àwọn ìpín yòókù láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn. Ibi mímọ́ yóo wà láàrin rẹ̀. Òòró ilẹ̀ tí ẹ óo yà sọ́tọ̀ fún OLUWA yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan (20,000) igbọnwọ (kilomita 10). Èyí yóo jẹ́ ilẹ̀ fún ibi mímọ́ mi, níbẹ̀ sì ni ìpín ti àwọn alufaa yóo wà, yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), ní ìhà àríwá, ní ìwọ̀ oòrùn, ìbú rẹ̀ yóo jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 5), ní ìlà oòrùn, ìbú rẹ̀ yóo jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 5), òòró rẹ̀ ní ìhà gúsù yóo sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½). Ibi mímọ́ OLUWA yóo wà ní ààrin rẹ̀. Yóo jẹ́ ti àwọn alufaa tí a yà sọ́tọ̀, àwọn ọmọ Sadoku tí wọ́n pa òfin mi mọ́, tí wọn kò sì ṣáko lọ bí àwọn ọmọ Lefi, nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ṣáko lọ. Lọ́tọ̀ ni a óo fún wọn ní ilẹ̀ tiwọn. Yóo jẹ́ ìpín tiwọn lára ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ fún OLUWA, ilẹ̀ mímọ́ jùlọ; yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ ti àwọn ọmọ Lefi. Àwọn ọmọ Lefi yóo ní ìpínlẹ̀ tiwọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ tí a pín fún àwọn alufaa, òòró rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 5). Wọn kò gbọdọ̀ tà ninu rẹ̀, wọn kò gbọdọ̀ fi yáwó, wọn kò sì gbọdọ̀ fún ẹlòmíràn lára ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ yìí; nítorí pé mímọ́ ni, ti OLUWA sì ni. Èyí tí ó kù lára ilẹ̀ náà tí ìbú rẹ̀ jẹ́ ẹẹdẹgbaata (5,000) igbọnwọ (kilomita 2½), tí òòró rẹ̀ sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), yóo wà fún lílò àwọn ará ìlú, fún ibùgbé ati ilẹ̀ tí ó yí ìlú ká. Láàrin rẹ̀ ni ìlú yóo wà. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu ẹ̀gbẹ́ mẹrẹẹrin ìlú náà yóo gùn ní ẹgbaa meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (4,500) igbọnwọ (mita 2,250), ati ti ìlà oòrùn, ati ti ìwọ̀ oòrùn, ati ti àríwá ati ti gúsù. Ilẹ̀ pápá yóo sì wà ní ẹ̀gbẹ́ mẹrẹẹrin ìlú náà, ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan yóo gùn ní igba ó lé aadọta (250) igbọnwọ (mita 125). Ilẹ̀ tí ó kù lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ mímọ́ náà yóo jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 5) ní ẹ̀gbẹ́ ìlà oòrùn, ati ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 5) ní ẹ̀gbẹ́ ìwọ̀ oòrùn. Yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ mímọ́ náà. Èso ilẹ̀ náà yóo jẹ́ oúnjẹ fún àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́ ninu ìlú. Àwọn òṣìṣẹ́ ààrin ìlú tí wọ́n bá wá láti inú àwọn ẹ̀yà Israẹli ni yóo máa dá oko níbẹ̀. Gbogbo ilẹ̀ tí ẹ óo yà sọ́tọ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½) ní òòró ati ìbú. Èyí ni àròpọ̀ ibi mímọ́ ati ilẹ̀ ti gbogbo ìlú náà. Ilẹ̀ tí ó kù lápá ọ̀tún ati apá òsì ilẹ̀ mímọ́ náà, ati ti ìlú yóo jẹ́ ti ọba. Ilẹ̀ náà yóo bẹ̀rẹ̀ láti ibi tí ilẹ̀ mímọ́ pin sí, lọ sí ààlà tí ó wà ní apá ìlà oòrùn, ati ibi tí ilẹ̀ mímọ́ náà pin sí, lọ sí ààlà tí ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn. Yóo wà ní ẹ̀gbẹ́ ilẹ̀ ti ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan; ilẹ̀ mímọ́ ati tẹmpili mímọ́ yóo sì wà láàrin rẹ̀. Ilẹ̀ àwọn ọmọ Lefi ati ilẹ̀ gbogbo ìlú yóo wà láàrin ilẹ̀ ọba. Ilẹ̀ ọba yóo wà láàrin ilẹ̀ Juda ati ti Bẹnjamini. Ní ti àwọn ẹ̀yà Israẹli yòókù, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn, Bẹnjamini yóo ní ìpín kan. Ìpín ti Simeoni yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Bẹnjamini, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn. Ìpín kan tí Isakari ní yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Simeoni, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn. Ìpín kan ti Sebuluni yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Isakari, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn. Ìpín kan ti Gadi yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Sebuluni, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn. Lẹ́gbẹ̀ẹ́ agbègbè Gadi ní ìhà gúsù, ààlà ilẹ̀ náà yóo lọ láti Tamari títí dé ibi àwọn odò Meriba Kadeṣi, títí dé àwọn odò Ijipti, tí ó fi lọ dé Òkun Ńlá. Ilẹ̀ tí ẹ óo pín láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli nìyí; bẹ́ẹ̀ sì ni ètò bí ẹ óo ṣe pín in fún olukuluku wọn, OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. Ìwọ̀nyí ni yóo jẹ́ ẹnubodè àbájáde ìlú náà. Apá ìhà àríwá tí ó jẹ́ ẹgbaa meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (4,500) igbọnwọ (mita 2,250), yóo ní ẹnubodè mẹta. Orúkọ wọn yóo máa jẹ́ ẹnubodè Reubẹni, ẹnubodè Juda ati ẹnubodè Lefi. Orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli ni a fi sọ àwọn ẹnu ọ̀nà ìlú. Apá ìlà oòrùn tí ó jẹ́ ẹgbaa meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (4,500) igbọnwọ (mita 2,250), yóo ní ẹnu ọ̀nà mẹta. Orúkọ wọn yóo máa jẹ́ ẹnubodè Josẹfu, ẹnubodè Bẹnjamini ati ẹnubodè Dani. Apá ìhà gúsù tí ó jẹ́ ẹgbaa meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (4,500) igbọnwọ (mita 2,250), yóo ní ẹnu ọ̀nà mẹta. Orúkọ wọn yóo máa jẹ́ ẹnubodè Simeoni, ẹnubodè Isakari ati ẹnubodè Sebuluni. Apá ìwọ̀ oòrùn tí ó jẹ́ ẹgbaa meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (4,500) igbọnwọ (mita 2,250), yóo ní ẹnubodè mẹta. Orúkọ wọn yóo máa jẹ́ ẹnubodè Gadi, ẹnubodè Aṣeri ati ẹnubodè Nafutali. Àyíká ìlú náà yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó dín ẹgbaa (18,000) igbọnwọ (mita 9,000). Orúkọ ìlú náà yóo máa jẹ́, “OLUWA Ń Bẹ Níbí.” Ní ọdún kẹta ìjọba Jehoiakimu ọba Juda, Nebukadinesari ọba Babiloni wá gbógun ti Jerusalẹmu, ó sì dótì í. OLUWA jẹ́ kí ọwọ́ rẹ̀ tẹ Jehoiakimu ọba Juda. Nebukadinesari kó ninu àwọn ohun èlò ilé Ọlọrun lọ sí ilẹ̀ Ṣinari, ó sì kó wọn sinu ilé ìṣúra tí ó wà ninu ilé oriṣa rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó pàṣẹ fún Aṣipenasi, olórí àwọn ìwẹ̀fà rẹ̀ pé kí ó lọ sí ààrin àwọn ọmọ ọba ati àwọn eniyan pataki pataki ninu àwọn ọmọ Israẹli, kí ó ṣa àwọn ọ̀dọ́ tí wọn kò ní àbùkù lára, àwọn tí wọ́n lẹ́wà, tí wọ́n sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n lọ́nà gbogbo, tí wọ́n ní ẹ̀bùn ìmọ̀, ati òye ẹ̀kọ́, tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ní ààfin ọba, kí á sì kọ́ wọn ní ìmọ̀ ati èdè àwọn ará Kalidea. Ọba ṣètò pé kí wọn máa gbé oúnjẹ aládùn pẹlu ọtí waini fún wọn lára oúnjẹ ati ọtí waini ti òun alára. Wọn óo kẹ́kọ̀ọ́ fún ọdún mẹta, lẹ́yìn náà, wọn óo máa ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ ọba. Daniẹli, ati Hananaya, ati Miṣaeli ati Asaraya wà lára àwọn tí wọ́n ṣà ninu ẹ̀yà Juda. Olórí àwọn ìwẹ̀fà sọ ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ titun: Ó sọ Daniẹli ní Beteṣasari, ó sọ Hananaya ní Ṣadiraki, ó sọ Miṣaeli ní Meṣaki, ó sì sọ Asaraya ni Abedinego. Daniẹli pinnu pé òun kò ní fi oúnjẹ aládùn tí ọba ń jẹ, tabi ọtí tí ó ń mu sọ ara òun di aláìmọ́. Nítorí náà, ó lọ bẹ Aṣipenasi, olórí àwọn ìwẹ̀fà ọba, pé kí ó gba òun láàyè kí òun má sọ ara òun di aláìmọ́. Ọlọrun jẹ́ kí Daniẹli bá ojurere ati àánú olórí àwọn ìwẹ̀fà náà pàdé. Ṣugbọn Aṣipenasi sọ fún Daniẹli, pé, ẹ̀rù ń ba òun, kí ọba tí ó ṣètò jíjẹ ati mímu Daniẹli ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ má baà lọ ṣe akiyesi pé Daniẹli rù ju àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lọ, kí òun má baà fi ẹ̀mí òun wéwu lọ́dọ̀ ọba. Nítorí náà, Daniẹli sọ fún ẹni tí olórí àwọn ìwẹ̀fà yàn láti máa tọ́jú òun ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹtẹẹta pé, “Dán àwa iranṣẹ rẹ wò fún ọjọ́ mẹ́wàá, máa fún wa ní ẹ̀wà jẹ, kí o sì máa fún wa ní omi lásán mu. Lẹ́yìn náà, kí o wá fi wá wé àwọn tí wọn ń jẹ lára oúnjẹ àdídùn tí ọba ń jẹ, bí o bá ti wá rí àwa iranṣẹ rẹ sí ni kí o ṣe ṣe sí wa.” Ó gba ohun tí wọ́n wí, ó sì dán wọn wò fún ọjọ́ mẹ́wàá. Lẹ́yìn ọjọ́ kẹwaa, ojú wọn rẹwà, wọ́n sì sanra ju gbogbo àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tí ń jẹ oúnjẹ àdídùn tí ọba ń jẹ lọ. Nítorí náà, ẹni tí ń tọ́jú wọn bẹ̀rẹ̀ sí fún wọn ní ẹ̀wà, dípò oúnjẹ aládùn tí wọn ìbá máa jẹ ati ọtí tí wọn ìbá máa mu. Ọlọrun fún àwọn ọdọmọkunrin mẹrẹẹrin yìí ní ọgbọ́n, ìmọ̀, ati òye; Daniẹli sì ní ìmọ̀ láti túmọ̀ ìran ati àlá. Nígbà tí ó tó àkókò tí ọba ti pàṣẹ pé kí wọ́n kó wọn wá, olórí ìwẹ̀fà kó gbogbo wọn wá siwaju rẹ̀. Ọba pè wọ́n, ó dán wọn wò, ninu gbogbo wọn, kò sì sí ẹni tí ó dàbí Daniẹli, Hananaya, Miṣaeli ati Asaraya. Nítorí náà, wọ́n fi Daniẹli ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ ọba ní ààfin. Ninu gbogbo ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ati ìmọ̀ tí ọba bi wọ́n, ó rí i pé wọ́n sàn ní ìlọ́po mẹ́wàá ju gbogbo àwọn pidánpidán ati àwọn aláfọ̀ṣẹ tí ó wà ní ìjọba rẹ̀ lọ. Daniẹli sì wà níbẹ̀ títí di ọdún kinni ìjọba Kirusi. Ní ọdún keji tí Nebukadinesari gun orí oyè, ó lá àwọn àlá kan; àlá náà bà á lẹ́rù tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi lè sùn mọ́ lóru ọjọ́ náà. Nítorí náà, ọba pàṣẹ pé kí wọ́n pe àwọn pidánpidán, ati àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn oṣó ati àwọn ará Kalidea jọ, kí wọ́n wá rọ́ àlá òun fún òun. Gbogbo wọn sì wá siwaju ọba. Ọba sọ fún wọn pé, “Mo lá àlá kan tí ó bà mí lẹ́rù pupọ, mo sì fẹ́ mọ ìtumọ̀ rẹ̀.” Àwọn ará Kalidea bá dá ọba lóhùn pé, “Kí ọba pẹ́! Rọ́ àlá rẹ fún àwa iranṣẹ rẹ, a óo sì túmọ̀ rẹ̀.” Ṣugbọn ọba dá wọn lóhùn, pé, “Ohun tí mo bá sọ abẹ ni ó gé e; bí ẹ kò bá lè rọ́ àlá náà fún mi, kí ẹ sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, n óo fà yín ya ní tapá-titan, ilé yín yóo sì di àlàpà. Ṣugbọn bí ẹ bá rọ́ àlá náà, tí ẹ sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, ẹ óo gba ẹ̀bùn, ìdálọ́lá ati ẹ̀yẹ ńlá, nítorí náà ẹ rọ́ àlá náà fún mi, kí ẹ sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀.” Wọ́n dá ọba lóhùn lẹẹkeji pé, “Kí kabiyesi rọ́ àlá rẹ̀ fún wa, a óo sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀.” Ọba dá wọn lóhùn pé, “Mo mọ̀ dájú pé ẹ kàn fẹ́ máa fi ọgbọ́n fi àkókò ṣòfò ni, nítorí ẹ ti mọ̀ pé bí mo ti wí ni n óo ṣe. Bí ẹ kò bá rọ́ àlá mi fún mi, ìyà kanṣoṣo ni n óo fi jẹ yín. Gbogbo yín ti gbìmọ̀ pọ̀ láti máa parọ́, ati láti máa fi ọgbọ́n fi àkókò ṣòfò. Ẹ rọ́ àlá mi fún mi, n óo sì mọ̀ dájú pé ẹ lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀.” Wọ́n dá ọba lóhùn pé, “Kò sí ẹni náà láyé yìí, tí ó lè sọ ohun tí kabiyesi fẹ́ kí á sọ, kò sí ọba ńlá tabi alágbára kankan tí ó tíì bèèrè irú nǹkan yìí lọ́wọ́ pidánpidán kan, tabi lọ́wọ́ àwọn aláfọ̀ṣẹ, tabi lọ́wọ́ àwọn ará Kalidea rí. Ohun tí ọba ń bèèrè yìí le pupọ, kò sí ẹni tí ó lè ṣe é, àfi àwọn oriṣa, nítorí pé àwọn kì í ṣe ẹlẹ́ran ara.” Nítorí náà inú ọba ru, ó sì bínú gidigidi, ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni run. Àṣẹ jáde lọ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n; wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí wá Daniẹli ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti pa wọ́n. Daniẹli bá lọ sí ọ̀dọ̀ Arioku, tí ọba pàṣẹ fún pé kí ó pa àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni; ó fi ọgbọ́n ati ìrẹ̀lẹ̀ bá a sọ̀rọ̀, ó ní, “Kí ló dé tí àṣẹ ọba fi le tó báyìí?” Arioku bá sọ bí ọ̀rọ̀ ti rí fún un. Lẹsẹkẹsẹ, Daniẹli lọ bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ ọba pé kí ó dá àkókò fún òun, kí òun lè wá rọ́ àlá náà fún ọba, kí òun sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀. Daniẹli bá lọ sí ilé, ó sọ fún àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀: Hananaya, Miṣaeli, ati Asaraya, pé kí wọ́n gbadura sí Ọlọrun ọ̀run fún àánú láti mọ àlá ọba ati ìtumọ̀ rẹ̀, kí wọ́n má baà pa òun ati àwọn ẹlẹgbẹ́ òun run pẹlu àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni. Ọlọrun bá fi àṣírí náà han Daniẹli ní ojúran, lóru. Ó sì yin Ọlọrun ọ̀run lógo. Ó ní, “Ẹni ìyìn ni Ọlọrun títí ayérayé, ẹni tí ó ní ọgbọ́n ati agbára. Òun ní ń yí ìgbà ati àkókò pada; òun níí mú ọba kan kúrò lórí ìtẹ́, tíí sì í fi òmíràn jẹ. Òun níí fi ọgbọ́n fún ọlọ́gbọ́n tíí sì í fi ìmọ̀ fún àwọn ọ̀mọ̀ràn. Òun níí fi àṣírí ati ohun ìjìnlẹ̀ hàn; ó mọ ohun tí ó wà ninu òkùnkùn, ìmọ́lẹ̀ sì ń bá a gbé. Ìwọ Ọlọrun àwọn baba mi, ni mo fi ọpẹ́ ati ìyìn fún, nítorí o fún mi ní ọgbọ́n ati agbára, o sì ti fi ohun tí a bèèrè hàn mí, nítorí o ti fi ohun tí ọba ń bèèrè hàn wá.” Daniẹli bá lọ sí ọ̀dọ̀ Arioku, ẹni tí ọba yàn pé kí ó pa àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni run, ó sọ fún un pé, “Má pa àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni run, mú mi lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, n óo sì túmọ̀ àlá rẹ̀ fún un.” Arioku bá mú Daniẹli lọ sí ọ̀dọ̀ ọba kíákíá. Ó sọ fún ọba pé: “Kabiyesi, mo ti rí ọkunrin kan ninu àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú wá láti Juda, tí ó le túmọ̀ àlá náà fún ọba.” Ọba bi Daniẹli, tí wọ́n sọ ní Beteṣasari ní èdè Babiloni pé, “Ǹjẹ́ o lè rọ́ àlá mi fún mi, kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀?” Daniẹli dá ọba lóhùn pé, “Kò sí ọlọ́gbọ́n kan, tabi aláfọ̀ṣẹ, tabi pidánpidán, tabi awòràwọ̀ tí ó lè sọ àṣírí ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ọba ń bèèrè yìí fún un. Ṣugbọn Ọlọrun kan ń bẹ ní ọ̀run, tí ń fi àṣírí nǹkan ìjìnlẹ̀ hàn. Òun ni ó fi ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la han Nebukadinesari ọba. Àlá tí o lá, ati ìran tí o rí ní orí ibùsùn rẹ nìyí: “Kabiyesi! Bí o ti sùn, ò ń ronú ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la, ẹni tí ń fi ohun ìjìnlẹ̀ han ni sì fi ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ hàn ọ́. Ní tèmi, kì í ṣe pé mo gbọ́n ju àwọn yòókù lọ ni a ṣe fi ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ yìí hàn mí, bíkòṣe pé kí ọba lè mọ ìtumọ̀ rẹ̀, kí òye ohun tí ó ń rò sì lè yé e. “Kabiyesi, o rí ère kan níwájú rẹ ní ojúran, ère yìí tóbi gan-an, ó mọ́lẹ̀, ó ń dán, ìrísí rẹ̀ sì bani lẹ́rù. Wúrà ni orí rẹ̀, àyà ati apá rẹ̀ jẹ́ fadaka, ikùn rẹ̀ títí dé itan sì jẹ́ idẹ. Irin ni òkè ẹsẹ̀ rẹ̀, ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ irin tí a lú pọ̀ mọ́ amọ̀. Bí o ti ń wò ó, òkúta kan là, ó sì ré bọ́ láti òkè, ó bá ère náà ní ẹsẹ̀ mejeeji tí ó jẹ́ àdàlú irin ati amọ̀, mejeeji sì fọ́ túútúú. Lẹ́sẹ̀kan náà òkúta yìí bá fọ́ gbogbo ère náà, ati irin, ati amọ̀, ati idẹ, ati fadaka ati wúrà, ó rún gbogbo wọn wómúwómú, títí wọ́n fi dàbí ìyàngbò ní ibi ìpakà. Lẹ́yìn náà, afẹ́fẹ́ fẹ́ wọn lọ, a kò sì rí wọn mọ́ rárá. Òkúta tí ó kọlu ère náà di òkè ńlá, ó sì bo gbogbo ayé. “Àlá náà nìyí; nisinsinyii, n óo sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọba. Kabiyesi, ìwọ ọba àwọn ọba ni Ọlọrun ọ̀run fún ní ìjọba, agbára, ipá ati ògo. Ọlọrun fi gbogbo eniyan jìn ọ́, níbi yòówù tí wọn ń gbé, ati gbogbo ẹranko, ati gbogbo ẹyẹ, pé kí o máa jọba lórí wọn, ìwọ ni orí wúrà náà. Lẹ́yìn rẹ ni ìjọba mìíràn yóo dìde tí kò ní lágbára tó tìrẹ. Lẹ́yìn èyí ni ìjọba kẹta, tí ó jẹ́ ti idẹ, yóo jọba lórí gbogbo ayé. Nígbà tí ó bá yá, ìjọba kẹrin yóo dé, tí yóo le koko bíi irin (nítorí pé irin a máa fọ́ nǹkan sí wẹ́wẹ́ ni); bíi irin ni ìjọba yìí yóo fọ́ àwọn tí wọ́n wà ṣáájú rẹ̀ túútúú. Bí o sì ti rí ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ ati ìka ẹsẹ̀ rẹ̀ tí ó jẹ́ àdàlú irin ati amọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba yìí yóo pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Ṣugbọn agbára irin yóo hàn lára rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí o ti rí i tí irin dàpọ̀ mọ́ amọ̀. Bí ìka ẹsẹ̀ rẹ̀ sì ti jẹ́ àdàlú amọ̀ ati irin, bẹ́ẹ̀ ni apá kan ìjọba náà yóo lágbára, apá kan kò sì ní lágbára. Bí o ti rí amọ̀ tí ó dàpọ̀ mọ́ irin, bẹ́ẹ̀ ni àwọn apá kinni keji yóo máa dàpọ̀ ní igbeyawo, ṣugbọn wọn kò ní darapọ̀, gẹ́gẹ́ bí irin kò ti lè darapọ̀ mọ́ amọ̀. Ní àkókò àwọn ìjọba wọnyi ni Ọlọrun ọ̀run yóo gbé ìjọba kan dìde tí a kò ní lè parun, a kò sì ní fi ìjọba náà fún ẹlòmíràn. Yóo fọ́ àwọn ìjọba wọnyi túútúú, yóo pa wọ́n run, yóo sì dúró laelae. Bí o ti rí i pé ara òkè kan ni òkúta yìí ti là, láìjẹ́ pé eniyan kan ni ó là á, tí o sì rí i pé ó fọ́ irin, idẹ, amọ̀, fadaka ati wúrà túútúú, Ọlọrun tí ó tóbi ni ó fi ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la han ọba. Òtítọ́ ni àlá yìí, ìtumọ̀ rẹ̀ sì dájú.” Ọba bá wólẹ̀ níwájú Daniẹli, ó fi orí balẹ̀ fún un, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n rúbọ kí wọ́n sì sun turari sí Daniẹli. Ọba sọ fún Daniẹli pé, “Láìsí àní àní, Ọlọrun rẹ ni Ọlọrun àwọn ọlọrun, ati OLUWA àwọn ọba, òun níí fi ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ han eniyan, nítorí pé àṣírí ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ yìí gan-an ni o sọ.” Ọba dá Daniẹli lọ́lá, ó kó oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn ńláńlá fún un, ó sì fi ṣe olórí gbogbo agbègbè Babiloni, ati olórí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ní Babiloni. Daniẹli gba àṣẹ lọ́wọ́ ọba, ó fi Ṣadiraki, Meṣaki, ati Abedinego ṣe alákòóso àwọn agbègbè Babiloni, ṣugbọn òun wà ní ààfin. Nebukadinesari fi kìkì wúrà yá ère kan tí ó ga ní ọgọta igbọnwọ (mita 27), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹfa (mita 2.7). Ó gbé e kalẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dura ní agbègbè Babiloni. Ó pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn baálẹ̀ agbègbè, àwọn olórí ati àwọn gomina, àwọn ìgbìmọ̀ ati àwọn akápò, àwọn onídàájọ́ ati àwọn alákòóso ati gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ọba tí wọ́n wà ní àwọn agbègbè Babiloni wá sí ibi ìyàsímímọ́ ère tí òun gbé kalẹ̀. Nítorí náà, gbogbo wọn wá sí ibi ìyàsímímọ́ ère náà, wọ́n sì dúró níwájú rẹ̀. Akéde bá kígbe sókè, ó kéde pé, “Ọba ní kí á pàṣẹ fun yín, gbogbo eniyan, ẹ̀yin orílẹ̀, ati oniruuru èdè pé nígbà tí ẹ bá gbọ́ ìró fèrè, dùùrù, ìlù, hapu, ati oniruuru orin, kí ẹ dojúbolẹ̀ kí ẹ sin ère wúrà tí ọba Nebukadinesari gbé kalẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí kò bá wólẹ̀, kí ó sin ère náà, lẹsẹkẹsẹ ni a óo gbé e sọ sinu adágún iná.” Nítorí náà, nígbà tí wọ́n gbọ́ ìró àwọn ohun èlò orin náà, gbogbo wọn wólẹ̀, wọ́n sì sin ère wúrà tí Nebukadinesari, ọba gbé kalẹ̀. Àwọn ará Kalidea kan wá siwaju ọba, wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọn Juu pẹlu ìríra, wọ́n ní, “Kí ọba kí ó pẹ́! Ìwọ ọba ni o pàṣẹ pé nígbàkúùgbà tí ẹnikẹ́ni bá ti gbọ́ ìró fèrè, dùùrù, ìlù, hapu, ati oniruuru orin, kí ó wólẹ̀, kí ó tẹríba fún ère tí o gbé kalẹ̀, ati pé ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, a óo sọ ọ́ sinu adágún iná tí ń jó. Àwọn Juu mẹta kan tí ń jẹ́ Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego, tí o fi ṣe alákòóso àwọn agbègbè ní ìjọba Babiloni tàpá sí àṣẹ ọba, wọn kò sin ère wúrà tí o gbé kalẹ̀.” Inú bí ọba gidigidi, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n kó àwọn mẹtẹẹta wá siwaju òun, wọ́n bá kó Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego lọ siwaju ọba. Ó bi wọ́n léèrè pé, “Ṣé nítòótọ́ ni ẹ kò fi orí balẹ̀, kí ẹ sì sin ère wúrà tí mo gbé kalẹ̀? Nisinsinyii, bí ẹ bá ti gbọ́ ìró ipè, fèrè, dùùrù, ìlù, hapu, ati oniruuru orin, tí ẹ bá wólẹ̀, tí ẹ sì sin ère tí mo ti yá, ó dára, ṣugbọn bí ẹ bá kọ̀, tí ẹ kò wólẹ̀, wọn óo gbe yín sọ sinu adágún iná ìléru. Kò sì sí ọlọrun náà tí ó lè gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi?” Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego dá ọba lóhùn pé, “Kabiyesi, kò yẹ kí á máa bá ọ jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí. Bí o bá sọ wá sinu iná, Ọlọrun wa tí à ń sìn lè yọ wá ninu adágún iná, ó sì lè gbà wá lọ́wọ́ ìwọ ọba pàápàá. Ṣugbọn bí kò bá tilẹ̀ gbà wá, a fẹ́ kí ọba mọ̀ pé a kò ní fi orí balẹ̀, kí á sin ère wúrà tí ó gbé kalẹ̀.” Inú bá bí Nebukadinesari gidigidi, ojú rẹ̀ yipada sí Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego. Ó pàṣẹ pé kí wọ́n dá iná, kí ó gbóná ní ìlọ́po meje ju bíí tií máa ń gbóná tẹ́lẹ̀ lọ. Ó tún pàṣẹ pé kí àwọn akọni ninu àwọn ọmọ ogun rẹ̀ di Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego, kí wọ́n sì sọ wọ́n sinu adágún iná. Wọ́n di àwọn mẹtẹẹta pẹlu agbádá, ati aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀, ati fìlà wọn, ati àwọn aṣọ wọn mìíràn, wọ́n sì sọ wọ́n sí ààrin adágún iná tí ń jó. Nítorí bí àṣẹ ọba ti le tó, ati bí adágún iná náà ti gbóná tó, ahọ́n iná tí ń jó bùlàbùlà jó àwọn tí wọ́n gbé Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego sinu rẹ̀ ní àjópa. Nítorí dídì tí wọ́n di Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego, wọ́n ṣubú lulẹ̀ sí ààrin iná náà. Lójijì Nebukadinesari ta gìrì, ó sáré dìde, ó sì bèèrè lọ́wọ́ àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ pé, “Ṣebí eniyan mẹta ni a dì, tí a gbé sọ sinu iná?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, kabiyesi.” Ó ní, “Ẹ wò ó, eniyan mẹrin ni mo rí yìí, wọ́n wà ní títú sílẹ̀, wọ́n ń rìn káàkiri láàrin iná, iná kò sì jó wọn, Ìrísí ẹni kẹrin dàbí ti ẹ̀dá ọ̀run.” Nebukadinesari ọba bá lọ sí ẹnu ọ̀nà adágún iná náà, ó kígbe pé, “Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego, ẹ̀yin iranṣẹ Ọlọrun alààyè, ẹ jáde wá!” Wọ́n bá jáde kúrò ninu iná lẹsẹkẹsẹ. Gbogbo àwọn baálẹ̀ ìgbèríko, àwọn olórí, àwọn gomina, ati àwọn ìgbìmọ̀ ọba, kó ara wọn jọ, wọ́n sì rí i pé iná kò jó àwọn ọkunrin wọnyi, irun orí wọn kò rùn, ẹ̀wù wọn kò yipada, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tilẹ̀ gbóòórùn iná lára wọn. Nebukadinesari bá dáhùn pé “Ògo ni fún Ọlọrun Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego tí ó rán angẹli rẹ̀ láti gba àwọn iranṣẹ rẹ̀, tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e, tí wọn kò ka àṣẹ ọba sí, tí wọ́n fi ẹ̀mí wọn wéwu, dípò kí wọ́n sin ọlọrun mìíràn yàtọ̀ sí Ọlọrun wọn. “Nítorí náà, mo pàṣẹ pé, ẹnikẹ́ni, tabi orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà tí ó bá sọ̀rọ̀ àbùkù sí Ọlọrun Ṣadiraki, Meṣaki ati ti Abedinego, fífà ni a ó fa irú ẹni bẹ́ẹ̀ ya ní tapá-titan, a ó sì sọ ilé rẹ̀ di ahoro; nítorí kò sí ọlọrun mìíràn tí ó lè gbani là bẹ́ẹ̀.” Ọba bá gbé Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego sí ipò gíga ní ìgbèríko Babiloni. Ọba Babiloni ranṣẹ sí gbogbo àwọn eniyan, ati gbogbo orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà ní gbogbo ayé, pé: “Kí alaafia wà pẹlu yín! Ó tọ́ lójú mi láti fi àmì ati iṣẹ́ ìyanu, tí Ọlọrun tí ó ga jùlọ ṣe fún mi, hàn. “Iṣẹ́ rẹ̀ tóbi gan-an! Iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ sì lágbára lọpọlọpọ! Títí ayérayé ni ìjọba rẹ̀, àtìrandíran rẹ̀ ni yóo sì máa jọba. “Èmi, Nebukadinesari wà ninu ìdẹ̀ra ní ààfin mi, nǹkan sì ń dára fún mi. Mo lá àlá kan tí ó bà mí lẹ́rù. Èrò ọkàn mi ati ìran tí mo rí lórí ibùsùn mi kó ìdààmú bá mi. Nítorí náà, mo pàṣẹ pé kí wọ́n kó gbogbo àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n Babiloni wá sọ́dọ̀ mi, kí wọ́n wá túmọ̀ àlá náà fún mi. Gbogbo àwọn pidánpidán, ati àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn ará Kalidea, ati àwọn awòràwọ̀ bá péjọ siwaju mi; mo rọ́ àlá náà fún wọn, ṣugbọn wọn kò lè túmọ̀ rẹ̀ fún mi. Lẹ́yìn gbogbo wọn patapata ni Daniẹli dé, tí a sọ ní Beteṣasari, orúkọ oriṣa mi, Daniẹli yìí ní ẹ̀mí Ọlọrun ninu. Mo rọ́ àlá mi fún un, mo ní: Beteṣasari, olórí gbogbo àwọn pidánpidán, mo mọ̀ pé ẹ̀mí Ọlọrun mímọ́ wà ninu rẹ, ati pé o mọ gbogbo àṣírí. Gbọ́ àlá mi kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi. “Nígbà tí mo sùn, mo rí igi kan láàrin ayé, lójú ìran, igi náà ga lọpọlọpọ. Igi náà bẹ̀rẹ̀ sí tóbi, ó sì lágbára; orí rẹ̀ kan ojú ọ̀run, kò sí ibi tí wọn kò ti lè rí i ní gbogbo ayé. Ewé rẹ̀ lẹ́wà, ó so jìnwìnnì, oúnjẹ wà lórí rẹ̀ fún gbogbo eniyan, abẹ́ rẹ̀ ni àwọn ẹranko ń gbé, orí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì ni àwọn ẹyẹ ń sùn. Èso rẹ̀ ni gbogbo ẹ̀dá alààyè ń jẹ. “Ní ojúran, lórí ibùsùn mi, mo rí olùṣọ́ kan, Ẹni Mímọ́, ó kígbe sókè pé, ‘Gé igi náà lulẹ̀, gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò, gbọn gbogbo ewé ati èso rẹ̀ dànù; kí àwọn ẹranko sá kúrò lábẹ́ rẹ̀, kí àwọn ẹyẹ sì fò kúrò lórí ẹ̀ka rẹ̀. Ṣugbọn fi kùkùté, ati gbòǹgbò rẹ̀ sílẹ̀ ninu ìdè irin ati ti idẹ ninu pápá. “ ‘Jẹ́ kí ìrì sẹ̀ sí i lára, kí ó máa bá àwọn ẹranko jẹ koríko; kí ọkàn rẹ̀ sì yipada kúrò ní ọkàn eniyan sí ti ẹranko fún ọdún meje. Láti ọ̀dọ̀ àwọn olùṣọ́ ni ìdájọ́ yìí ti wá, ìpinnu náà jẹ́ ti àwọn Ẹni Mímọ́; kí gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè lè mọ̀ pé Ẹni Gíga Jùlọ ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wù ú níí máa gbé ìjọba lé lọ́wọ́, pàápàá láàrin àwọn ẹni tí ó rẹlẹ̀ jùlọ.’ “Ìran tí èmi Nebukadinesari rí nìyí. Ìwọ Beteṣasari, sọ ìtumọ̀ rẹ̀, nítorí gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n ìjọba mi kò lè túmọ̀ rẹ̀ fún mi. Ṣugbọn o lè ṣe é, nítorí pé ẹ̀mí Ọlọrun mímọ́ wà ninu rẹ.” Ọkàn Daniẹli, tí wọn ń pè ní Beteṣasari, pòrúúruù fún ìgbà díẹ̀, ẹ̀rù sì bà á. Ọba bá sọ fún un pé: “Má jẹ́ kí àlá yìí ati ìtumọ̀ rẹ̀ bà ọ́ lẹ́rù.” Beteṣasari dáhùn pé, “olúwa mi, kí àlá yìí ṣẹ mọ́ àwọn tí wọ́n kórìíra rẹ lára, kí ìtumọ̀ rẹ̀ sì dà lé àwọn ọ̀tá rẹ lórí. Igi tí o rí, tí ó dàgbà, tí ó lágbára, tí orí rẹ̀ sì kan ọ̀run dé ibi pé gbogbo eniyan lè rí i, tí ewé rẹ̀ lẹ́wà, tí ó so jìnwìnnì, tí èso rẹ̀ jẹ́ oúnjẹ fún gbogbo ẹ̀dá, tí gbogbo àwọn ẹranko ń gbé abẹ́ rẹ̀, tí àwọn ẹyẹ sì ń sùn lórí àwọn ẹ̀ka rẹ̀. “Ìwọ ọba ni igi yìí, ìwọ ni o dàgbà, tí o di igi ńlá, tí o sì lágbára. Òkìkí rẹ kàn dé ọ̀run, ìjọba rẹ sì kárí gbogbo ayé. Olùṣọ́, Ẹni Mímọ́ tí ọba rí tí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run, tí ó ń wí pé, ‘Gé igi náà lulẹ̀ kí o sì pa á run, ṣugbọn kí ó ku kùkùté ati gbòǹgbò rẹ̀ ninu ilẹ̀, kí ó wà ninu ìdè irin ati ti idẹ, ninu pápá oko tútù, kí ìrì sẹ̀ sí i lára, kí ó máa bá àwọn ẹranko jẹ káàkiri fún ọdún meje.’ “Kabiyesi, ìtumọ̀ rẹ̀ nìyí: Àṣẹ tí Ẹni Gíga Jùlọ pa nípa oluwa mi, ọba ni. A óo lé ọ jáde kúrò láàrin àwọn eniyan, o óo sì máa bá àwọn ẹranko inú igbó gbé; o óo máa jẹ koríko bíi mààlúù, ìrì yóo sì sẹ̀ sí ọ lára fún ọdún meje, títí tí o óo fi mọ̀ pé Ẹni Gíga Jùlọ ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, ẹni tí ó bá wù ú níí sì í gbé e lé lọ́wọ́. Olùṣọ́ náà pàṣẹ pé kí á fi gbòǹgbò igi náà sílẹ̀ ninu ilẹ̀; ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, dájúdájú, o óo tún pada wá jọba, nígbà tí o bá gbà pé Ọlọrun ni ọba gbogbo ayé. Nítorí náà, kabiyesi, gba ìmọ̀ràn tí n óo fún ọ yìí; jáwọ́ ninu ẹ̀ṣẹ̀, sì máa ṣe òdodo, jáwọ́ ninu ìwà ìkà, máa ṣàánú fún àwọn tí a ni lára, bóyá èyí lè mú kí àkókò alaafia rẹ gùn sí i.” Gbogbo nǹkan wọnyi sì ṣẹ mọ́ Nebukadinesari ọba lára. Ní ìparí oṣù kejila, bí ó ti ń rìn lórí òrùlé ààfin Babiloni, ó ní, “Ẹ wo bí Babiloni ti tóbi tó, ìlú tí mo fi ipá ati agbára mi kọ́, tí mo sọ di olú-ìlú fún ògo ati ọlá ńlá mi.” Kí ó tó wí bẹ́ẹ̀ tán, ẹnìkan fọhùn láti ọ̀run, ó ní, “Nebukadinesari ọba, gbọ́ ohun tí a ti pinnu nípa rẹ: a ti gba ìjọba kúrò lọ́wọ́ rẹ, a óo lé ọ kúrò láàrin àwọn eniyan, o óo máa bá àwọn ẹranko gbé, o óo sì máa jẹ koríko bíi mààlúù fún ọdún meje, títí tí o óo fi mọ̀ pé, Ẹni Gíga Jùlọ ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, ati pé ẹni tí ó bá wù ú ní í máa gbé e lé lọ́wọ́.” Lẹsẹkẹsẹ ni ọ̀rọ̀ náà ṣẹ mọ́ Nebukadinesari lára. Wọ́n lé e kúrò láàrin àwọn eniyan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ koríko bíi mààlúù. Ìrì sẹ̀ sí i lára títí tí irun orí rẹ̀ fi gùn bí ìyẹ́ idì, èékánná rẹ̀ sì dàbí ti ẹyẹ. Nebukadinesari ní, “Lẹ́yìn ọdún meje náà, èmi, Nebukadinesari, gbé ojú sí òkè ọ̀run, iyè mi pada bọ̀ sípò. Mo yin Ẹni Gíga Jùlọ, mo fi ọlá ati ògo fún Ẹni Ayérayé. “Ìjọba ayérayé ni ìjọba rẹ̀ láti ìrandíran ni ìjọba rẹ̀, àní, láti ìrandíran ni ìjọba rẹ̀. Gbogbo aráyé kò jámọ́ nǹkankan lójú rẹ̀; a sì máa ṣe bí ó ti wù ú láàrin àwọn aráyé ati láàrin àwọn ogun ọ̀run. Kò sí ẹni tí ó lè ká a lọ́wọ́ kò, tabi tí ó lè yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ wò. “Ní àkókò gan-an tí iyè mi pada bọ̀ sípò, ògo, ọlá, ati iyì ìjọba mi náà sì tún pada sọ́dọ̀ mi. Àwọn ìgbìmọ̀ ati àwọn ìjòyè mi wá mi kàn, wọ́n gbà mí tọwọ́ tẹsẹ̀, ìjọba mi tún fi ìdí múlẹ̀, mo sì níyì ju ti àtẹ̀yìnwá lọ ní gbogbo ọ̀nà. “Ẹ gbọ́, èmi Nebukadinesari, fi ìyìn, ògo, ati ọlá fún ọba ọ̀run. Nítorí pé gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ pé, ọ̀nà rẹ̀ tọ́, ó sì lè rẹ àwọn agbéraga sílẹ̀.” Ní ọjọ́ kan, Beṣasari ọba, se àsè ńlá kan fún ẹgbẹrun (1,000) ninu àwọn ìjòyè rẹ̀, ó sì ń mu ọtí níwájú wọn. Nígbà tí ó tọ́ ọtí náà wò, ó pàṣẹ pé kí wọn kó àwọn ife wúrà ati ti fadaka tí Nebukadinesari, baba rẹ̀, kó wá láti inú tẹmpili ní Jerusalẹmu jáde, kí òun, ati àwọn ìjòyè òun, àwọn ayaba ati àwọn obinrin òun lè máa fi wọ́n mu ọtí. Wọ́n bá kó àwọn ife wúrà ati ti fadaka tí wọ́n kó ninu tẹmpili ní Jerusalẹmu jáde, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n mu ọtí. Bí wọn tí ń mu ọtí, ni wọ́n ń yin ère wúrà, ère fadaka, ère irin, ère igi, ati ère òkúta. Lẹsẹkẹsẹ, ọwọ́ kan bẹ̀rẹ̀ sí kọ̀wé sí ara ògiri ààfin níbi tí iná fìtílà tan ìmọ́lẹ̀ sí, ọba rí ọwọ́ náà, bí ó ti ń kọ̀wé. Ojú ọba yipada, ẹ̀rù bà á, ara rẹ̀ ń gbọ̀n, orúnkún rẹ̀ sì ń lu ara wọn. Ó kígbe sókè pé kí wọ́n tètè lọ pe àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn ará Kalidea ati àwọn awòràwọ̀ wá. Nígbà tí wọ́n dé, ọba sọ fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá lè ka ohun tí wọ́n kọ sára ògiri yìí, tí ó sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, n óo fi aṣọ elése àlùkò dá a lọ́lá, n óo ní kí wọ́n fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn, yóo sì wà ní ipò kẹta sí ọba ninu ìjọba mi.” Gbogbo àwọn amòye ọba wá, wọn kò lè ka àwọn àkọsílẹ̀ náà, wọn kò sì lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọba. Ọkàn Beṣasari dàrú, ojú rẹ̀ yipada. Àwọn ìjòyè rẹ̀ dààmú, wọn kò sì mọ ohun tí wọ́n lè ṣe. Nígbà tí ayaba gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀, ó wọ inú gbọ̀ngàn àsè náà, ó sọ fún ọba pé, “Kabiyesi, kí ọba kí ó pẹ́, má jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí dààmú rẹ tabi kí ó mú kí ojú rẹ fàro. Ẹnìkan ń bẹ ní ìjọba rẹ tí ó ní ẹ̀mí Ọlọrun Mímọ́ ninu. Ní àkókò baba rẹ, a rí ìmọ́lẹ̀, ìmọ̀, ati ọgbọ́n bíi ti Ọlọrun ninu rẹ̀. Òun ni baba rẹ, Nebukadinesari ọba, fi ṣe olórí gbogbo àwọn pidánpidán, àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn Kalidea ati àwọn awòràwọ̀; nítorí pé Daniẹli, tí ọba sọ ní Beteṣasari, ní ìmọ̀ ati òye láti túmọ̀ àlá, ati láti ṣe àlàyé ohun ìjìnlẹ̀, ati láti yanjú ọ̀rọ̀ tí ó bá díjú. Ranṣẹ pe Daniẹli yìí, yóo sì sọ ìtumọ̀ fún ọ.” Wọ́n bá mú Daniẹli wá siwaju ọba. Ọba bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé “Ṣé ìwọ ni Daniẹli, ọ̀kan ninu àwọn ẹrú, tí baba mi kó wá láti ilẹ̀ Juda? Mo ti gbọ́ pé ẹ̀mí Ọlọrun Mímọ́ ń bẹ ninu rẹ; ati pé o ní ìmọ̀, òye, ati ọgbọ́n tí kò lẹ́gbẹ́. Gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n ati aláfọ̀ṣẹ wá siwaju mi, wọ́n gbìyànjú láti ka àkọsílẹ̀ yìí, kí wọ́n sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, ṣugbọn kò sí ẹni tí ó lè ṣe é. Mo ti gbọ́ nípa rẹ pé o lè túmọ̀ ohun ìjìnlẹ̀, o sì lè yanjú ọ̀rọ̀ tí ó bá díjú; nisinsinyii, bí o bá lè ka àkọsílẹ̀ yìí, kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, wọn óo wọ̀ ọ́ ní aṣọ elése àlùkò, wọn óo sì fi ẹ̀gbà wúrà sí ọ lọ́rùn, o óo sì wà ní ipò kẹta sí ọba ní ìjọba mi.” Daniẹli dá ọba lóhùn, ó ní, “Jẹ́ kí ẹ̀bùn rẹ máa gbé ọwọ́ rẹ, kí o sì fi ọrẹ rẹ fún ẹlòmíràn. Ṣugbọn n óo ka àkọsílẹ̀ náà fún ọba, n óo sì túmọ̀ rẹ̀. “Kabiyesi, Ọlọrun tí ó ga jùlọ fún Nebukadinesari, baba rẹ ní ìjọba, ó sọ ọ́ di ẹni ńlá, ó fún un ní ògo ati ọlá. Nítorí pé Ọlọrun sọ ọ́ di ẹni ńlá, gbogbo eniyan, gbogbo orílẹ̀-èdè ati gbogbo ẹ̀yà ń tẹríba fún un tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù. A máa pa ẹni tí ó bá fẹ́, a sì máa dá ẹni tí ó fẹ́ sí. A máa gbé ẹni tí ó bá fẹ́ ga, a sì máa rẹ ẹni tí ó bá wù ú sílẹ̀. Ṣugbọn nígbà tí ó gbé ara rẹ̀ ga, tí ó sì ṣe oríkunkun, a mú un kúrò lórí ìtẹ́ rẹ̀, a sì mú ògo rẹ̀ kúrò. A lé e kúrò láàrin àwọn ọmọ eniyan, ọkàn rẹ̀ dàbí ti ẹranko. Ó ń bá àwọn ẹranko gbé inú igbó. Ó ń jẹ koríko bíi mààlúù, ìrì sì sẹ̀ sí i lára, títí ó fi mọ̀ pé Ọlọrun tí ó ga jùlọ, ni ó ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, tí ó sì ń gbé e fún ẹni tí ó bá wù ú. “Bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ ọmọ rẹ̀ Beṣasari, o kọ̀, o kò rẹ ara rẹ sílẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Ò ń gbéraga sí Ọlọrun ọ̀run. O ranṣẹ lọ kó àwọn ohun èlò ilé Ọlọrun wá siwaju rẹ. Ìwọ ati àwọn ìjòyè rẹ, àwọn ayaba ati àwọn obinrin rẹ, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n mu ọtí waini. Ẹ sì ń yin àwọn oriṣa fadaka, ti wúrà, ti idẹ, ti irin, ti igi ati ti òkúta. Wọn kò ríran wọn kò gbọ́ràn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀. O kò yin Ọlọrun tí ẹ̀mí rẹ wà lọ́wọ́ rẹ̀ lógo, ẹni tí ó mọ gbogbo ọ̀nà rẹ. Ìdí nìyí tí ó fi rán ọwọ́ kan jáde láti kọ àkọsílẹ̀ yìí. “Ohun tí a kọ náà nìyí: ‘MENE, MENE, TEKELI, PERESINI.’ Ìtumọ̀ rẹ̀ sì nìyí: MENE, Ọlọrun ti ṣírò àwọn ọjọ́ ìjọba rẹ, ó sì ti parí rẹ̀. TEKELI, a ti wọ̀n ọ́ lórí ìwọ̀n, o kò sì kún ojú ìwọ̀n. PERESINI, a ti pín ìjọba rẹ, a sì ti fún àwọn ará Mede ati àwọn ará Pasia.” Beṣasari bá pàṣẹ, pé kí wọ́n gbé ẹ̀wù elése àlùkò, ti àwọn olóyè, wọ Daniẹli, kí wọ́n sì fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn. Wọ́n kéde ká gbogbo ìjọba pé Daniẹli ni igbá kẹta ní ìjọba. Ní alẹ́ ọjọ́ náà gan-an ni wọ́n pa Beṣasari, ọba àwọn ará Kalidea. Dariusi, ará Mede, ẹni ọdún mejilelọgọta sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Dariusi ṣètò láti yan ọgọfa (120) gomina láti ṣe àkóso ìjọba rẹ̀. Ó yan àwọn mẹta láti máa ṣe àbojútó gbogbo wọn, Daniẹli sì jẹ́ ọ̀kan ninu wọn. Àwọn mẹta wọnyi ni àwọn ọgọfa (120) gomina náà yóo máa jábọ̀ fún. Ṣugbọn Daniẹli tún ta gbogbo àwọn alámòójútó ati gomina náà yọ nítorí ẹ̀mí tí kò lẹ́gbẹ́ tí ó wà ninu rẹ̀. Ọba sì ń gbèrò láti fi gbogbo ọ̀rọ̀ ìjọba lé e lọ́wọ́. Nítorí náà, àwọn alabojuto ati àwọn gomina wọnyi ń wá ẹ̀sùn sí Daniẹli lẹ́sẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ ìjọba, ṣugbọn wọn kò rí ẹ̀sùn kankan tí wọ́n lè kà sí i lẹ́sẹ̀. Wọn kò ká ohunkohun mọ́ ọn lọ́wọ́ nítorí olóòótọ́ eniyan ni. Wọn kò bá àṣìṣe kankan lọ́wọ́ rẹ̀. Wọ́n sọ fún ara wọn pé, “A kò ní rí ẹ̀sùn kà sí Daniẹli lẹ́sẹ̀, àfi ohun tí ó bá jẹmọ́ òfin Ọlọrun rẹ̀.” Nítorí náà, àwọn alabojuto ati àwọn gomina gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n kó ara wọn jọ sọ́dọ̀ ọba, wọ́n wí fún un pé “Dariusi ọba, kí ọba pẹ́, gbogbo àwọn alabojuto, àwọn olórí, àwọn ìgbìmọ̀, ati àwọn gomina kó ara wọn jọ, wọ́n sì fi ohùn ṣọ̀kan pé kí ọba ṣe òfin kan pé, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ bèèrè ohunkohun lọ́wọ́ oriṣa kankan tabi eniyan kankan fún ọgbọ̀n ọjọ́, bíkòṣe lọ́wọ́ òun ọba. Ẹni tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, kabiyesi, kí wọ́n jù ú sinu ihò kinniun. Nisinsinyii, kabiyesi, ẹ fi ọwọ́ sí òfin yìí, kí ó lè fi ìdí múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òfin Mede ati Pasia tí kò gbọdọ̀ yipada.” Nítorí náà, Dariusi ọba fi ọwọ́ sí òfin náà, ó sì fi òǹtẹ̀ tẹ̀ ẹ́. Nígbà tí Daniẹli gbọ́ pé wọ́n ti fi ọwọ́ sí òfin náà, ó lọ sí ilé rẹ̀, ó wọ yàrá òkè lọ, ó ṣí fèrèsé ilé rẹ̀ sílẹ̀, sí apá Jerusalẹmu. Ó kúnlẹ̀, ó ń gbadura, ó sì ń yin Ọlọrun, nígbà mẹta lojoojumọ. Àwọn ọkunrin wọnyi bá kó ara wọn jọ. Wọ́n wá wo Daniẹli níbi tí ó ti ń gbadura, tí ó sì ń bẹ̀bẹ̀ níwájú Ọlọrun rẹ̀. Wọ́n wá siwaju ọba, wọ́n sọ nípa àṣẹ tí ó pa pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ bèèrè ohunkohun lọ́wọ́ oriṣa kankan tabi eniyan kankan fún ọgbọ̀n ọjọ́, bíkòṣe lọ́wọ́ rẹ̀, ati pé ẹnikẹ́ni tí ó bá rú òfin yìí, a óo jù ú sinu ihò kinniun. Ọba dáhùn, ó ní: “Dájúdájú, òfin Mede ati Pasia ni, tí a kò lè yipada.” Wọ́n bá sọ fún ọba pé, “Daniẹli, ọ̀kan ninu àwọn ìgbèkùn Juda kò kà ọ́ sí, kò sì pa òfin rẹ mọ́. Ṣugbọn ìgbà mẹta lóòjọ́ níí máa gbadura.” Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ọkàn rẹ̀ dàrú lọpọlọpọ, ó sa gbogbo ipá rẹ̀ títí ilẹ̀ fi ṣú láti gba Daniẹli sílẹ̀. Àwọn ọkunrin wọnyi gbìmọ̀, wọ́n sọ fún ọba pé, “Kabiyesi, o mọ̀ pé òfin Mede ati ti Pasia ni pé òfin tí ọba bá ṣe kò gbọdọ̀ yipada.” Ọba bá pàṣẹ pé kí wọ́n lọ mú Daniẹli, kí wọ́n sì jù ú sinu ihò kinniun. Ṣugbọn ó sọ fún Daniẹli pé, “Ọlọrun rẹ tí ò ń sìn láìsinmi yóo gbà ọ́.” Wọ́n yí òkúta dí ẹnu ihò kinniun náà. Ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀ sì fi òǹtẹ̀ òrùka wọn tẹ ọ̀dà tí wọ́n yọ́ lé e, kí ẹnikẹ́ni má lè gba Daniẹli sílẹ̀. Ọba bá lọ sí ààfin rẹ̀, ó fi gbogbo òru náà gbààwẹ̀. Kò jẹ́ kí àwọn eléré ṣe eré níwájú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì lè sùn. Bí ilẹ̀ ti mọ́, ọba dìde, ó sáré lọ sí ibi ihò kinniun náà. Nígbà tí ó dé ẹ̀bá ibẹ̀, ó kígbe pẹlu ohùn arò, ó ní, “Daniẹli, iranṣẹ Ọlọrun Alààyè, ǹjẹ́ Ọlọrun tí ò ń sìn láìsinmi gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn kinniun?” Daniẹli dáhùn pé, “Kabiyesi, kí ọba pẹ́, Ọlọrun mi ti rán angẹli rẹ̀, ó ti dí àwọn kinniun lẹ́nu, wọn kò sì pa mí lára. Nítorí pé n kò jẹ̀bi níwájú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì ṣe nǹkan burúkú sí ìwọ ọba.” Inú ọba dùn pupọ, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n yọ Daniẹli jáde. Wọ́n bá yọ Daniẹli jáde kúrò ninu ihò kinniun, àwọn kinniun kò sì pa á lára rárá, nítorí pé ó gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun rẹ̀. Ọba bá pàṣẹ pé kí wọ́n lọ mú gbogbo àwọn tí wọ́n fi ẹ̀sùn kan Daniẹli, ati àwọn ọmọ wọn, ati àwọn aya wọn, wọ́n bá dà wọ́n sinu ihò kinniun. Kí wọn tó dé ìsàlẹ̀, àwọn kinniun ti bò wọ́n mọ́lẹ̀, wọ́n sì fọ́ egungun wọn túútúú. Dariusi ọba bá kọ ìwé sí gbogbo eniyan ní gbogbo orílẹ̀-èdè ati gbogbo ẹ̀yà tí ó wà ní orí ilẹ̀ ayé ó ní, “Kí alaafia wà pẹlu yín, mo pàṣẹ pé ní gbogbo ìjọba mi, kí gbogbo eniyan máa wárìrì níwájú Ọlọrun Daniẹli, kí wọ́n sì máa bẹ̀rù rẹ̀. “Nítorí òun ni Ọlọrun Alààyè tí ó wà títí ayérayé. Ìjọba rẹ̀ kò lè parun lae, àṣẹ rẹ̀ yóo sì máa wà títí dé òpin. Ó ń gbani là, ó ń dáni nídè. Ó ń ṣiṣẹ́ àánú tí ó yani lẹ́nu ní ọ̀run ati ní ayé. Òun ni ó gba Daniẹli lọ́wọ́ agbára kinniun.” Nǹkan sì ń dára fún Daniẹli ní àkókò Dariusi ati Kirusi, àwọn ọba Pasia. Ní ọdún kinni tí Beṣasari jọba ní Babiloni, Daniẹli lá àlá, o sì rí àwọn ìran kan nígbà tí ó sùn lórí ibùsùn rẹ̀. Ó bá kọ kókó ohun tí ó rí lójú àlá náà sílẹ̀. Ó ní, “Bí mo ti sùn ní alẹ́, mo rí i lójúran pé afẹ́fẹ́ tí ń fẹ́ láti igun mẹrẹẹrin ayé ń rú omi òkun ńlá sókè. Àwọn ẹranko ńláńlá mẹrin bá jáde láti inú òkun. Ọ̀kan kò jọ̀kan ni àwọn mẹrẹẹrin. Ekinni dàbí kinniun, ó sì ní ìyẹ́ bíi ti idì. Mò ń wò ó títí tí ìyẹ́ rẹ̀ fi fà tu. A gbé e dìde lórí ẹsẹ̀ rẹ̀ mejeeji bí eniyan. Ó sì ń ronú bí eniyan. “Ẹranko keji dàbí àmọ̀tẹ́kùn, ó gbé ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kan sókè. Ó gbé egungun ìhà mẹta há ẹnu, ó wa eyín mọ́ ọn. Mo sì gbọ́ tí ẹnìkan sọ fún un pé, ‘Dìde, kí o sì máa jẹ ẹran sí i.’ “Bí mo ti ń wò mo tún rí ẹranko mìíràn tí ó dàbí ẹkùn, òun náà ní ìyẹ́ mẹrin lẹ́yìn. Ó ní orí mẹrin. A sì fún un ní agbára láti jọba. “Lẹ́yìn èyí, ninu ìran tí mo rí ní òru náà, ẹranko kẹrin tí mo rí jáni láyà, ó bani lẹ́rù, ó sì lágbára pupọ. Ó tóbi, irin sì ni eyín rẹ̀. A máa fọ́ nǹkan túútúú, á jẹ ẹ́ ní àjẹrun, á sì fi ẹsẹ̀ tẹ àjẹkù rẹ̀ mọ́lẹ̀. Ó yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ẹranko tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀, ìwo mẹ́wàá ni ó ní. Bí mo ti ń ronú nípa àwọn ìwo rẹ̀, ni mo rí i tí ìwo kékeré kan tún hù láàrin wọn, ìwo mẹta fà tu níwájú rẹ̀ ninu àwọn ìwo ti àkọ́kọ́. Ìwo kékeré yìí ní ojú bí eniyan, ó sì ní ẹnu tí ó fi ń sọ ọ̀rọ̀ ńláńlá. “Bí mo ti ń wo ọ̀kánkán, mo rí àwọn ìtẹ́ kan tí a tẹ́. Ẹni Ayérayé sì jókòó lórí ìtẹ́ tirẹ̀, aṣọ rẹ̀ funfun bíi ẹ̀gbọ̀n òwú. Irun orí rẹ̀ náà dàbí irun aguntan funfun, ìtẹ́ rẹ̀ ń jó bí ahọ́n iná, kẹ̀kẹ́ abẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sì dàbí iná. Iná ń ṣàn jáde bí odò níwájú rẹ̀. Ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀nà ẹgbẹẹgbẹrun ni àwọn tí ń ṣe iranṣẹ fún un, ọ̀kẹ́ àìmọye sì ni àwọn tí wọ́n dúró níwájú rẹ̀. Ìdájọ́ bẹ̀rẹ̀, a sì ṣí àwọn ìwé sílẹ̀. “Mo wò yíká nítorí ọ̀rọ̀ ńláńlá tí ìwo kékeré yìí ń fi ẹnu sọ, mo sì rí i tí wọ́n pa ẹranko náà, tí wọ́n sì jó òkú rẹ̀ níná. Ní ti àwọn ẹranko tí ó kù, a gba àṣẹ wọn, ṣugbọn a dá wọn sí fún àkókò kan, àní fún ìgbà díẹ̀. “Ninu ìran, lóru, mo rí ẹnìkan tí ó rí bí Ọmọ Eniyan ninu awọsanma, ó lọ sí ọ̀dọ̀ Ẹni Ayérayé náà, ó sì fi ara rẹ̀ hàn níwájú rẹ̀. A sì fún Ẹni Ayérayé ní àṣẹ, ògo ati ìjọba, pé kí gbogbo eniyan ní gbogbo orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà máa sìn ín. Àṣẹ ayérayé tí kò lè yẹ̀ ni àṣẹ rẹ̀, ìjọba rẹ̀ kò sì lè parun. “Ìran tí mo rí yìí bà mí lẹ́rù pupọ, ọkàn mi sì dààmú. Mo bá súnmọ́ ọ̀kan ninu àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀, mo bèèrè ìtumọ̀ ohun tí mo rí, ó sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, ó ní, ‘Àwọn ọba ńlá mẹrin tí yóo jẹ láyé ni àwọn ẹranko ńláńlá mẹrin tí o rí. Ṣugbọn àwọn eniyan mímọ́ Ẹni Gíga Jùlọ yóo gba ìjọba ayé, ìjọba náà yóo jẹ́ tiwọn títí lae, àní títí ayé àìlópin.’ “Mo tún fẹ́ mọ̀ nípa ẹranko kẹrin, tí ó yàtọ̀ sí gbogbo àwọn yòókù, tí ó bani lẹ́rù lọpọlọpọ, tí èékánná rẹ̀ jẹ́ idẹ, tí eyín rẹ̀ sì jẹ́ irin; tí ń jẹ àjẹrun, tí ó ń fọ́ nǹkan túútúú, tí ó sì ń fi ẹsẹ̀ tẹ àjẹkù rẹ̀ mọ́lẹ̀. Mo fẹ́ mọ̀ nípa àwọn ìwo mẹ́wàá orí rẹ̀, ati ìwo kékeré, tí ó fa mẹta tí ó wà níwájú rẹ̀ tu, tí ó ní ojú, tí ń fi ẹnu rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀ ńláńlá, tí ó sì dàbí ẹni pé ó ju gbogbo àwọn yòókù lọ. “Bí mo ti ń wò ó, mo rí i ti ìwo yìí ń bá àwọn eniyan mímọ́ jà, tí ó sì ń ṣẹgun wọn, títí tí Ẹni Ayérayé fi dé, tí ó dá àwọn ẹni mímọ́ ti Ẹni Gíga Jùlọ láre; tí ó sì tó àkókò fún àwọn ẹni mímọ́ láti gba ìjọba. “Ó ṣe àlàyé rẹ̀ fún mi báyìí pé: ‘Ẹranko kẹrin ni ìjọba kẹrin tí yóo wà láyé, tí yóo sì yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ìyókù. Yóo ṣẹgun gbogbo ayé, yóo tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, yóo sì fọ́ ọ túútúú. Àwọn ìwo mẹ́wàá dúró fún àwọn ọba mẹ́wàá, tí yóo jáde lára ìjọba kẹrin yìí. Ọ̀kan yóo jáde lẹ́yìn wọn, tí yóo yàtọ̀ sí wọn, yóo sì borí mẹta ninu àwọn ọba náà. Yóo sọ̀rọ̀ òdì sí Ẹni Gíga Jùlọ, yóo sì dá àwọn eniyan mímọ́, ti Ẹni Gíga Jùlọ lágara. Yóo gbìyànjú láti yí àkókò ati òfin pada. A óo sì fi wọ́n lé e lọ́wọ́ fún ọdún mẹta ati ààbọ̀. Ṣugbọn ìdájọ́ yóo bẹ̀rẹ̀, a óo gba àṣẹ kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, a óo sì pa á run patapata. A óo fi ìjọba ati àṣẹ, ati títóbi àwọn ìjọba tí ó wà láyé fún àwọn eniyan mímọ́ ti Ẹni Gíga Jùlọ, ìjọba ayérayé ni ìjọba wọn yóo jẹ́, gbogbo àwọn aláṣẹ yóo máa sìn ín, wọn yóo sì máa gbọ́ tirẹ̀.’ “Òpin ọ̀rọ̀ nípa ìran náà nìyí. Ẹ̀rù èrò ọkàn mi bà mí gidigidi, tóbẹ́ẹ̀ tí ojú mi yipada, ṣugbọn inú ara mi ni mo mọ ọ̀rọ̀ náà sí.” Ní ọdún kẹta tí Beṣasari jọba ni èmi Daniẹli rí ìran kan lẹ́yìn ti àkọ́kọ́. Ninu ìran náà, mo rí i pé mo wà ní Susa, olú-ìlú tí ó wà ní agbègbè Elamu. Mo rí i pé mo wà létí odò Ulai. Bí mo ti gbé ojú sókè, mo rí i tí àgbò kan dúró létí odò, ó ní ìwo meji tí ó ga sókè, ṣugbọn ọ̀kan gùn ju ekeji lọ. Èyí tí ó gùn jù ni ó hù kẹ́yìn. Mo rí i tí àgbò náà bẹ̀rẹ̀ sí kàn sí ìhà ìwọ̀ oòrùn, ati sí ìhà àríwá ati sí ìhà gúsù, kò sí ẹranko tí ó lè dúró níwájú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó lè gbani sílẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bí ó ti wù ú, ó sì ń gbéraga. Bí mo tí ń ronú nípa rẹ̀, mo rí i tí òbúkọ kan ti ìhà ìwọ̀ oòrùn la gbogbo ayé kọjá wá láìfi ẹsẹ̀ kan ilẹ̀, ó sì ní ìwo ńlá kan láàrin ojú rẹ̀ mejeeji. Ó súnmọ́ àgbò tí ó ní ìwo meji, tí mo kọ́ rí tí ó dúró létí odò, ó sì pa kuuru sí i pẹlu ibinu ńlá. Mo rí i ó súnmọ́ àgbò náà, ó fi tìbínú-tìbínú kàn án, ìwo mejeeji àgbò náà sì ṣẹ́. Àgbò náà kò lágbára láti dúró níwájú rẹ̀. Ó tì í ṣubú, ó sì ń fi ẹsẹ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀. Kò sì sí ẹni tí ó lè gba àgbò náà lọ́wọ́ rẹ̀. Òbúkọ náà bẹ̀rẹ̀ sí tóbi sí i, ṣugbọn nígbà tí agbára rẹ̀ dé góńgó, ìwo ńlá iwájú rẹ̀ bá kán. Ìwo ńlá mẹrin mìíràn sì hù dípò rẹ̀. Wọ́n kọjú sí ọ̀nà mẹrẹẹrin tí afẹ́fẹ́ ti ń fẹ́ wá. Lára ọ̀kan ninu àwọn ìwo mẹrin ọ̀hún ni ìwo kékeré kan ti yọ jáde, ó gbilẹ̀ lọ sí ìhà gúsù, sí ìhà ìlà oòrùn ati sí Ilẹ̀ Ìlérí náà. Ó tóbi pupọ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi ń bá àwọn ogun ọ̀run jà, ó já àwọn kan ninu àwọn ìràwọ̀ lulẹ̀, ó sì fi ẹsẹ̀ tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀. Ó gbé ara rẹ̀ ga, títí dé ọ̀dọ̀ olórí àwọn ogun ọ̀run. Ó gbé ẹbọ sísun ojoojumọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì gba ibi mímọ́ rẹ̀. A fi ogun náà ati ẹbọ sísun ojoojumọ lé e lọ́wọ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀, a sì já òtítọ́ lulẹ̀. Gbogbo ohun tí ìwo náà ń ṣe, ni ó ṣe ní àṣeyọrí. Ẹni mímọ́ kan sọ̀rọ̀; mo tún gbọ́ tí ẹni mímọ́ mìíràn dá ẹni tí ó kọ́ sọ̀rọ̀ lóhùn pé, “Ìran nípa ẹbọ sísun ojoojumọ yóo ti pẹ́ tó; ati ti ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ń sọ nǹkan di ahoro; ati ìran nípa pípa ibi mímọ́ tì, ati ti àwọn ọmọ ogun tí wọ́n di ìtẹ̀mọ́lẹ̀?” Mo gbọ́ tí ẹni mímọ́ náà dáhùn pé, “Nǹkan wọnyi yóo máa rí báyìí lọ títí fún ẹgbaa ó lé ọọdunrun (2,300) ọdún, lẹ́yìn náà a óo ya ibi mímọ́ sí mímọ́.” Nígbà tí èmi Daniẹli rí ìran náà, bí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí wá ọ̀nà láti mọ ìtumọ̀ rẹ̀, ni ẹnìkan bá yọ níwájú mi tí ó dàbí eniyan. Mo gbóhùn ẹnìkan láàrin bèbè kinni keji odò Ulai tí ó wí pé, “Geburẹli, sọ ìtumọ̀ ìran tí ọkunrin yìí rí fún un.” Ó wá sí ẹ̀bá ibi tí mo dúró sí. Bí mo ti rí i, ẹ̀rù bà mí, mo dojúbolẹ̀. Ó bá sọ fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, mo fẹ́ kí o mọ̀ pé ìran ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la ni ohun tí o rí.” Bí ó ti ń bá mi sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, mo sùn lọ fọnfọn, mo dojúbolẹ̀. Ó bá fọwọ́ kàn mí, ó sì gbé mi dìde, ó ní, “Ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ kẹ́yìn ibinu Ọlọrun sí àwọn eniyan lẹ́yìn ọ̀la ni ìran tí o rí. “Àwọn ọba Pasia ati Media ni àgbò tí o rí, tí ó ní ìwo meji lórí. Ìjọba Giriki ni òbúkọ onírun jákujàku tí o rí. Ọba àkọ́kọ́ tí yóo jẹ níbẹ̀ ni ìwo ńlá tí ó wà láàrin ojú rẹ̀. Ìtumọ̀ ìwo tí ó ṣẹ́, tí mẹrin mìíràn sì hù dípò rẹ̀, ni pé lẹ́yìn ikú rẹ̀ ni ìjọba rẹ̀ yóo pín sí mẹrin, ṣugbọn kò ní jẹ́ láti ọwọ́ rẹ̀. “Nígbà tí ìjọba wọn bá ń lọ sópin, tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn bá kún ojú ìwọ̀n, ọba kan tí ojú rẹ̀ le, tí ó ní àrékérekè, tí ó sì lágbára yóo gorí oyè. Agbára rẹ̀ yóo pọ̀, ṣugbọn kò ní jẹ́ nípa ipá rẹ̀, yóo máa ṣe àṣeyọrí ninu gbogbo ohun tí ó bá ń ṣe, yóo sì mú kí á run àwọn eniyan Ọlọrun ati àwọn alágbára. Nípa ọgbọ́n àrékérekè rẹ̀, yóo máa tan àwọn eniyan jẹ, ìgbéraga yóo kún ọkàn rẹ̀, yóo máa pa ọpọlọpọ eniyan lójijì, yóo sì lòdì sí ọba tí ó ju gbogbo àwọn ọba lọ. Ṣugbọn yóo parun láìní ọwọ́ ẹnikẹ́ni ninu. Ìran ti ẹbọ àṣáálẹ́ ati ti òwúrọ̀ tí a ti là yé ọ yóo ṣẹ dájúdájú; ṣugbọn, pa àṣírí ìran yìí mọ́ nítorí ọjọ́ tí yóo ṣẹ ṣì jìnnà.” Àárẹ̀ mú èmi Daniẹli, mo sì ṣàìsàn fún ọpọlọpọ ọjọ́. Nígbà tó yá, mo bá tún dìde, mò ń bá iṣẹ́ tí ọba yàn mí sí lọ, ṣugbọn ìran náà dẹ́rù bà mí, kò sì yé mi. Ní ọdún kinni tí Dariusi, ọmọ Ahasu-erusi, ará Mede, jọba ní Babiloni, èmi, Daniẹli bẹ̀rẹ̀ sí ka ọ̀rọ̀ OLUWA, mò ń ronú lórí ohun tí Jeremaya, wolii sọ, pé Jerusalẹmu yóo dahoro fún aadọrin ọdún. Mo bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ OLUWA Ọlọrun tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ mò ń gbadura tọkàntọkàn pẹlu ààwẹ̀; mo wọ aṣọ ọ̀fọ̀, mo sì jókòó sinu eérú. Mo gbadura sí OLUWA Ọlọrun mi, mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan mi. Mo ní, “OLUWA Ọlọrun, tí ó tóbi, tí ó bani lẹ́rù, tíí máa ń pa majẹmu ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ pẹlu gbogbo àwọn tí ó bá fẹ́ ẹ, tí wọ́n sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́. “A ti ṣẹ̀, a ti ṣe burúkú; a ti ṣìṣe, a ti ṣọ̀tẹ̀, nítorí pé a ti kọ òfin ati àṣẹ rẹ sílẹ̀. A kò fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn iranṣẹ rẹ, àní àwọn wolii, tí wọ́n wá jíṣẹ́ rẹ fún àwọn ọba wa ati àwọn olórí wa, àwọn baba wa, ati fún gbogbo àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà. Olódodo ni ọ́, OLUWA, ṣugbọn lónìí yìí ojú ti gbogbo àwọn ará Juda ati Jerusalẹmu, ati gbogbo Israẹli; ati àwọn tí wọ́n wà nítòsí ati àwọn tí wọ́n wà ní ọ̀nà jíjìn, níbi gbogbo tí o fọ́n wọn káàkiri sí nítorí ìwà ọ̀dàlẹ̀ tí wọ́n hù sí ọ. OLUWA, ìtìjú yìí pọ̀ fún àwọn ọba wa, àwọn olórí wa, ati àwọn baba wa, nítorí a ti ṣẹ̀ ọ́. Aláàánú ni ọ́ OLUWA Ọlọrun wa, ò sì máa dáríjì ni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ. A kò gbọ́ tìrẹ OLUWA Ọlọrun wa, bẹ́ẹ̀ ni a kò pa òfin rẹ tí o fi rán àwọn wolii, iranṣẹ rẹ sí wa mọ́. Gbogbo Israẹli ti rú òfin rẹ, wọ́n ti pada lẹ́yìn rẹ, wọ́n kọ̀, wọn kò gbọ́ tìrẹ. Nítorí náà, ègún ati ìbúra tí Mose, iranṣẹ rẹ kọ sinu ìwé òfin ti ṣẹ mọ́ wa lára. Ohun tí o sọ pé o óo ṣe sí àwa ati àwọn ọba wa náà ni o ṣe sí wa, tí àjálù ńlá fi dé bá wa. Irú ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Jerusalẹmu yìí kò ṣẹlẹ̀ sí ìlú kan rí, ninu gbogbo àwọn ìlú ayé yìí. Gbogbo ìyọnu tí a kọ sinu òfin Mose ti dé bá wa, sibẹ a kò wá ojurere OLUWA Ọlọrun wa, kí á yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí á sì tẹ̀lé ọ̀nà òtítọ́ rẹ̀. Nítorí náà, OLUWA ti mú kí ìyọnu dé bá wa, ó sì rọ̀jò rẹ̀ lé wa lórí; olódodo ni OLUWA Ọlọrun wa ninu gbogbo iṣẹ́ rẹ̀, sibẹ a kò tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ̀. “Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun wa, ìwọ tí o kó àwọn eniyan rẹ jáde ní ilẹ̀ Ijipti pẹlu agbára ńlá, nítorí orúkọ rẹ tí à ń ranti títí di òní, a ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe nǹkan burúkú. OLUWA, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ òdodo rẹ, dáwọ́ ibinu ati ìrúnú rẹ dúró lórí Jerusalẹmu, ìlú rẹ, òkè mímọ́ rẹ; nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ ati àìdára àwọn baba wa, ti sọ Jerusalẹmu ati àwọn eniyan rẹ, di àmúpòwe láàrin àwọn tí ó yí wa ká. Nítorí náà Ọlọrun wa, jọ̀wọ́ gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ iranṣẹ rẹ. Nítorí orúkọ rẹ, OLUWA, ṣí ojurere wo ibi mímọ́ rẹ tí ó ti di ahoro. Gbọ́ tiwa, Ọlọrun mi, ṣíjú wò wá, bí àwa ati ìlú tí à ń pe orúkọ rẹ mọ́, ti wà ninu ìsọdahoro. Kì í ṣe nítorí òdodo wa ni a ṣe ń gbadura sí ọ, ṣugbọn nítorí pé aláàánú ni ọ́. Gbọ́ tiwa, OLUWA, dáríjì wá, tẹ́tí sí wa, OLUWA, wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ yìí, má sì jẹ́ kí ó pẹ́, nítorí orúkọ rẹ, tí a fi ń pe ìlú rẹ ati àwọn eniyan rẹ.” Mo bẹ̀rẹ̀ sí gbadura, mò ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ èmi ati ti àwọn ọmọ Israẹli, eniyan mi, mo kó ẹ̀bẹ̀ mi tọ OLUWA Ọlọrun mi lọ, nítorí òkè mímọ́ rẹ̀. Bí mo ti ń gbadura, ni Geburẹli, tí mo rí lójúran ní àkọ́kọ́ bá yára fò wá sọ́dọ̀ mi, ní àkókò ẹbọ àṣáálẹ́. Ó wá ṣe àlàyé fún mi, ó ní, “Daniẹli, àlàyé ìran tí o rí ni mo wá ṣe fún ọ. Bí o ti bẹ̀rẹ̀ sí gbadura ni àṣẹ dé, òun ni mo sì wá sọ fún ọ́; nítorí àyànfẹ́ ni ọ́. Nisinsinyii, farabalẹ̀ ṣàkíyèsí ọ̀rọ̀ náà, kí òye ìran náà sì yé ọ. “Ọlọrun ti fi àṣẹ sí i pé, lẹ́yìn aadọrin ọdún lọ́nà meje ni òun óo tó dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan rẹ ati ti ìlú mímọ́ rẹ jì wọ́n, tí òun óo ṣe ètùtù fún ìwà burúkú wọn, tí òun óo mú òdodo ainipẹkun ṣẹ, tí òun óo fi èdìdì di ìran ati àsọtẹ́lẹ̀ náà, tí òun óo sì fi òróró ya Ilé Mímọ́ Jùlọ rẹ̀ sọ́tọ̀. Mọ èyí, kí ó sì yé ọ, pé láti ìgbà tí àṣẹ bá ti jáde lọ láti tún Jerusalẹmu kọ́, di ìgbà tí ẹni àmì òróró Ọlọrun, tíí ṣe ọmọ Aládé, yóo dé, yóo jẹ́ ọdún meje lọ́nà meje. Lẹ́yìn náà, ọdún mejilelọgọta lọ́nà meje ni a óo sì fi tún un kọ́, yóo ní òpópónà, omi yóo sì yí i po; ṣugbọn yóo jẹ́ àkókò ìyọnu. Lẹ́yìn ọdún mejilelọgọta lọ́nà meje yìí, wọn óo pa ẹni àmì òróró Ọlọrun kan láìṣẹ̀. Àwọn ọmọ ogun alágbára kan tí yóo joyè, yóo pa Jerusalẹmu ati Tẹmpili run. Òpin óo dé bá a bí àgbàrá òjò, ogun ati ìsọdahoro tí a ti fi àṣẹ sí yóo dé. Ìjòyè yìí yóo bá ọpọlọpọ dá majẹmu ọdún meje tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀. Fún ìdajì ọdún meje náà, yóo fi òpin sí ẹbọ rírú ati ọrẹ. Olùsọdahoro yóo gbé ohun ìríra ka téńté orí pẹpẹ ní Jerusalẹmu. Ohun ìríra náà yóo sì wà níbẹ̀ títí tí ìgbẹ̀yìn tí Ọlọrun ti fàṣẹ sí yóo fi dé bá olùsọdahoro náà.” Ní ọdún kẹta tí Kirusi jọba ní Pasia, Daniẹli, (tí à ń pè ní Beteṣasari) rí ìran kan. Òtítọ́ ni ìran náà, ó ṣòro láti túmọ̀, ṣugbọn a la ìran náà ati ìtumọ̀ rẹ̀ yé Daniẹli. Ní àkókò náà, èmi Daniẹli ń ṣọ̀fọ̀ fún ọ̀sẹ̀ mẹta. N kò jẹ oúnjẹ aládùn, n kò jẹran, n kò mu ọtí, n kò sì fi òróró para ní odidi ọ̀sẹ̀ mẹtẹẹta náà. Ní ọjọ́ kẹrinlelogun oṣù kinni ọdún tí à ń wí yìí, mo dúró létí odò Tigirisi. Bí mo ti gbójú sókè, mo rí ọkunrin kan tí ó wọ aṣọ funfun, ó fi àmùrè wúrà ṣe ìgbànú. Ara rẹ̀ ń dán bí òkúta olówó iyebíye tí à ń pè ní bẹrili. Ojú rẹ̀ ń kọ mànà bíi mànàmáná, ẹyinjú rẹ̀ sì ń tàn bí iná. Ọwọ́ ati ẹsẹ̀ rẹ̀ dàbí idẹ dídán, ohùn rẹ̀ sì dàbí ohùn ọpọlọpọ eniyan. Èmi nìkan ni mo rí ìran yìí, àwọn tí wọ́n wà pẹlu mi kò rí i, ṣugbọn ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì sápamọ́. Èmi nìkan ni mo kù tí mo sì rí ìran ńlá yìí. Kò sí agbára kankan fún mi mọ́; ojú mi sì yipada, ó wá rẹ̀ mí dẹẹ. Mo bá gbọ́ tí ó sọ̀rọ̀, nígbà tí mo gbọ́ ohùn rẹ̀, mo dojúbolẹ̀, oorun sì gbé mi lọ. Ọwọ́ kan bá dì mí mú, ó gbé mi nílẹ̀, mo da ọwọ́ ati orúnkún mi délẹ̀. Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n fún ìbẹ̀rù. Ẹni náà pè mí, ó ní, “Daniẹli, ẹni tí Ọlọrun fẹ́ràn! Dìde nàró kí o gbọ́ ohun tí n óo sọ fún ọ, nítorí ìwọ ni a rán mi sí.” Bí ó ti ń bá mi sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, mo dìde nàró, ṣugbọn mo ṣì tún ń gbọ̀n. Ó bá dá mi lọ́kàn le, ó ní, “Má bẹ̀rù, Daniẹli, nítorí láti ọjọ́ tí o ti pinnu láti mòye, tí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Ọlọrun rẹ, gbogbo ohun tí ò ń bèèrè ni a ti gbọ́, adura rẹ ni mo sì wá dáhùn. Angẹli, aláṣẹ ìjọba Pasia dè mí lọ́nà fún ọjọ́ mọkanlelogun; ṣugbọn Mikaeli, ọ̀kan ninu àwọn olórí aláṣẹ, ni ó wá ràn mí lọ́wọ́; nítorí wọ́n dá mi dúró sọ́dọ̀ aláṣẹ ìjọba Pasia. Kí o lè mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí àwọn eniyan rẹ lẹ́yìn ọ̀la ni mo ṣe wá, nítorí ìran ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú ni ìran tí o rí.” Nígbà tí ó bá mi sọ̀rọ̀ tán, mo dojúbolẹ̀, mo sì ya odi. Ẹnìkan tí ó dàbí eniyan wá, ó fi ọwọ́ kàn mí ní ètè; ẹnu mi bá yà, mo sì sọ̀rọ̀. Mo sọ fún ẹni tí ó dúró tì mí pé, “Olúwa mi, gbogbo ara ni ó wó mi, nítorí ìran tí mo rí, ó sì ti rẹ̀ mí patapata. N kò ní agbára kankan mọ́, kò sì sí èémí kankan ninu mi, báwo ni èmi iranṣẹ rẹ ti ṣe lè bá ìwọ oluwa mi sọ̀rọ̀?” Ẹni tí ó dàbí eniyan bá tún fi ọwọ́ kàn mí, ó sì fún mi ní okun. Ó ní, “Ìwọ tí Ọlọrun fẹ́ràn, má bẹ̀rù, alaafia ni, dá ara yá, kí o sì ṣe ọkàn gírí.” Nígbà tí ó bá mi sọ̀rọ̀ tán, mo tún lágbára sí i; mo bá dáhùn pé, “olúwa mi, máa sọ ọ̀rọ̀ rẹ lọ, nítorí ìwọ ni ó fún mi lágbára sí i.” Ó bi mí pé, “Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí mo fi tọ̀ ọ́ wá? Nisinsinyii n óo pada lọ bá aláṣẹ ìjọba Pasia jà, tí mo bá bá a jà tán, aláṣẹ ìjọba Giriki yóo wá. Kò sí ẹni tí yóo gbèjà mi ninu nǹkan wọnyi àfi Mikaeli, olùṣọ́ Israẹli; Ṣugbọn n óo sọ ohun tí ó wà ninu Ìwé Òtítọ́ fún ọ. “Ní ọdún kinni ìjọba Dariusi ará Mede, mo dúró tì í láti mú un lọ́kàn le ati láti bá a fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀. Nisinsinyii, n óo fi òtítọ́ hàn ọ́.” Angẹli náà tún ní, “Àwọn ọba mẹta ni yóo jẹ sí i ní Pasia; ẹkẹrin yóo ní ọrọ̀ pupọ ju gbogbo àwọn yòókù lọ; nígbà tí ó bá sì ti ipa ọrọ̀ rẹ̀ di alágbára tán, yóo ti gbogbo eniyan nídìí láti bá ìjọba Giriki jagun. “Ọba olókìkí kan yóo wá gorí oyè, pẹlu ipá ni yóo máa fi ṣe ìjọba tirẹ̀, yóo sì máa ṣe bí ó bá ti wù ú. Lẹ́yìn tí ó bá jọba, ìjọba rẹ̀ yóo pín sí ọ̀nà mẹrin. Àwọn ọba tí yóo jẹ lẹ́yìn rẹ̀ kò ní jẹ́ láti inú ìran rẹ̀, kò sì ní sí èyí tí yóo ní agbára tó o ninu wọn; nítorí a óo gba ìjọba rẹ̀, a óo sì fún àwọn ẹlòmíràn. “Ọba Ijipti ní ìhà gúsù yóo lágbára, ṣugbọn ọ̀kan ninu àwọn ìjòyè rẹ̀ yóo lágbára jù ú lọ, ìjọba rẹ̀ yóo sì tóbi ju ti ọba lọ. Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, ọba Ijipti yóo ní àjọṣepọ̀ pẹlu ọba Siria, ní ìhà àríwá, ọmọbinrin ọba Ijipti yóo wá sí ọ̀dọ̀ ọba Siria láti bá a dá majẹmu alaafia; ṣugbọn agbára ọmọbinrin náà yóo dínkù, ọba pàápàá ati ọmọ rẹ̀ kò sì ní tọ́jọ́. A óo kọ obinrin náà sílẹ̀, òun ati àwọn iranṣẹ rẹ̀, ati ọmọ rẹ̀, ati alátìlẹ́yìn rẹ̀. Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ yóo jọba ní ipò rẹ̀, yóo wá pẹlu ogun, yóo wọ ìlú olódi ọba Siria, yóo bá wọn jagun, yóo sì ṣẹgun wọn. Yóo kó àwọn oriṣa wọn, ati àwọn ère wọn lọ sí ilẹ̀ Ijipti, pẹlu àwọn ohun èlò olówó iyebíye wọn tí wọ́n fi wúrà ati fadaka ṣe; kò sì ní bá ọba Siria jagun mọ́ fún ọdún bíi mélòó kan. Ọba Siria yóo wá gbógun ti ọba Ijipti, ṣugbọn yóo sá pada sí ilẹ̀ rẹ̀. “Àwọn ọmọ ọba Siria yóo gbá ogun ńlá jọ, wọn yóo sì kó ogun wọn wá, wọn yóo jà títí wọn yóo fi wọ ìlú olódi ti ọ̀tá wọn. Inú yóo bí ọba Ijipti, yóo sì lọ bá ọba Siria jagun. Ọba Siria yóo kó ọpọlọpọ ogun jọ, ṣugbọn Ijipti yóo ṣẹgun rẹ̀. Ọba Ijipti óo máa gbéraga nítorí ìṣẹ́gun rẹ̀ lórí ọpọlọpọ ogun yìí, yóo sì pa ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun, ṣugbọn kò ní borí. “Nítorí pé ọba Siria yóo tún pada lọ, yóo kó ogun jọ, tí yóo pọ̀ ju ti iṣaaju lọ. Nígbà tí ó bá yá, lẹ́yìn ọpọlọpọ ọdún, yóo pada wá pẹlu ikọ̀ ọmọ ogun tí ó lágbára, pẹlu ọpọlọpọ ihamọra ati ohun ìjà. Ní àkókò náà, ọ̀pọ̀ eniyan yóo dìde sí ọba Ijipti; àwọn oníjàgídíjàgan láàrin àwọn eniyan rẹ̀ yóo dìde kí ìran yìí lè ṣẹ; ṣugbọn wọn kò ní borí. Ọba Siria yóo wá dóti ìlú olódi kan, yóo sì gbà á. Àwọn ọmọ ogun Ijipti kò ní lágbára láti dojú ìjà kọ ọ́, àwọn akikanju wọn pàápàá kò ní lágbára mọ́ láti jagun. Ọba Siria yóo ṣe wọ́n bí ó ti fẹ́ láìsí àtakò, yóo dúró ní Ilẹ̀ Dáradára náà, gbogbo rẹ̀ yóo sì wà ní ìkáwọ́ rẹ̀. “Ọba Siria yóo múra láti wá pẹlu gbogbo agbára ìjọba rẹ̀, yóo bá ọba Ijipti dá majẹmu alaafia, yóo sì mú majẹmu náà ṣẹ. Yóo fi ọmọbinrin rẹ̀ fún ọba Ijipti ní aya, kí ó lè ṣẹgun ọba Ijipti. Ṣugbọn yóo kùnà ninu ète rẹ̀. Lẹ́yìn náà, yóo bá àwọn orílẹ̀-èdè ati àwọn ilẹ̀ tí ó wà ní etíkun jà, yóo sì ṣẹgun ọpọlọpọ wọn. Ṣugbọn olórí-ogun kan yóo ṣẹgun rẹ̀, yóo sì pa òun náà run. Yóo pada sí ìlú olódi ti ara rẹ̀, ṣugbọn ijamba yóo ṣe é, yóo sì ṣubú lójú ogun; yóo sì fi bẹ́ẹ̀ parẹ́ patapata. “Ọba mìíràn yóo jẹ lẹ́yìn rẹ̀, yóo sì rán agbowóopá kan kí ó máa gba owó-odè kiri ní gbogbo ìjọba rẹ̀; ní kò pẹ́ kò jìnnà, a óo pa ọba náà, ṣugbọn kò ní jẹ́ ní gbangba tabi lójú ogun.” Angẹli náà tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ báyìí pé, “Ọba tí yóo tún jẹ ní Siria yóo jẹ́ ọba burúkú. Kì í ṣe òun ni oyè yóo tọ́ sí, ṣugbọn yóo dé lójijì, yóo sì fi àrékérekè gba ìjọba. Yóo tú àwọn ọmọ ogun ká níwájú rẹ̀, ati ọmọ aládé tí wọn bá dá majẹmu. Yóo máa fi ẹ̀tàn bá àwọn orílẹ̀-èdè dá majẹmu. Yóo sì bẹ̀rẹ̀ sí gbilẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè tí ó jọba lé lórí kéré. Lójijì yóo wá sí àwọn ibi tí ó ní ọrọ̀ jùlọ ní agbègbè náà, yóo máa ṣe ohun tí àwọn baba ńlá rẹ̀ kò ṣe rí. Yóo máa pín ìkógun rẹ̀ fún wọn. Yóo máa wá ọ̀nà ti yóo fi gba àwọn ìlú olódi; ṣugbọn fún ìgbà díẹ̀ ni. “Yóo fi gbogbo agbára ati ìgboyà rẹ̀ gbé ogun ńlá ti ọba Ijipti; ọba Ijipti náà yóo gbé ogun ńlá tì í, ṣugbọn kò ní lè dúró níwájú ọba Ijipti nítorí pé wọn yóo dìtẹ̀ mọ́ ọn. Àwọn tí wọ́n ń bá a jẹ oúnjẹ àdídùn pọ̀ gan-an ni yóo dìtẹ̀ mọ́ ọn; gbogbo ogun rẹ̀ ni yóo túká, ọpọlọpọ yóo sì kú. Àwọn ọba mejeeji ni yóo pinnu láti hùwà àrékérekè, wọn ó sì máa purọ́ tan ara wọn jẹ níbi tí wọ́n ti jọ ń jẹun; ṣugbọn òfo ni ọgbọ́n àrékérekè wọn yóo já sí; nítorí pé òpin wọn yóo dé ní àkókò tí a ti pinnu. Ọba Siria yóo wá pada sí ilẹ̀ rẹ̀ pẹlu gbogbo ìkógun rẹ̀. Ṣugbọn yóo pinnu ní ọkàn rẹ̀ láti gbógun ti majẹmu mímọ́ Ọlọrun ati Israẹli. Nígbà tí ó bá ṣe bí ó ti fẹ́ tán, yóo pada sí ilẹ̀ rẹ̀. “Ní àkókò tí a ti pinnu, yóo tún gbógun ti ilẹ̀ Ijipti, ṣugbọn nǹkan kò ní rí bíi ti àkọ́kọ́ fún un; nítorí pé, àwọn ọmọ ogun Kitimu tí wọ́n wà ninu ọkọ̀ ojú omi yóo gbógun tì í. “Ẹ̀rù yóo bà á, yóo sì sá pada, yóo fi ibinu ńlá gbógun ti majẹmu mímọ́ Ọlọrun ati Israẹli, yóo sì máa tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn tí wọ́n ti kọ majẹmu náà sílẹ̀. Àwọn kan ninu àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yóo wá, wọn yóo sọ Tẹmpili ati ibi ààbò di aláìmọ́, wọn yóo dáwọ́ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo dúró, wọn yóo sì gbé ohun ìríra tíí fa ìsọdahoro kalẹ̀. Pẹlu ẹ̀tàn, ọba yìí yóo mú àwọn tí wọ́n kọ majẹmu náà sílẹ̀ lọ́rẹ̀ẹ́; ṣugbọn àwọn tí wọ́n mọ Ọlọrun yóo dúró ṣinṣin, wọn óo sì ṣe ẹ̀tọ́. Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọlọ́gbọ́n láàrin wọn óo máa la ọpọlọpọ lọ́yẹ, ṣugbọn fún ìgbà díẹ̀, wọn óo kú ikú idà, a óo dáná sun wọ́n, a óo kó wọn lẹ́rù, a óo sì kó wọn ní ẹrú lọ. Nígbà tí a bá ṣẹgun wọn, wọn yóo rí ìrànlọ́wọ́ díẹ̀ gbà, ọpọlọpọ yóo sì faramọ́ wọn pẹlu ẹ̀tàn. Díẹ̀ ninu àwọn ọlọ́gbọ́n yóo kú lójú ogun, a óo fi dán àwọn ọmọ Israẹli wò láti wẹ̀ wọ́n mọ́ ati láti mú gbogbo àbààwọ́n wọn kúrò títí di àkókò ìkẹyìn, ní àkókò tí Ọlọrun ti pinnu. “Ohun tí ó bá wu ọba náà ni yóo máa ṣe; yóo gbé ara rẹ̀ ga ju gbogbo oriṣa lọ, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo máa sọ̀rọ̀ tó lòdì sí Ọlọrun àwọn ọlọrun, yóo sì bẹ̀rẹ̀ sí lágbára sí i títí ọjọ́ ibinu tí a dá fún un yóo fi pé; nítorí pé ohun tí Ọlọrun ti pinnu yóo ṣẹ. Kò ní náání oriṣa tí àwọn baba rẹ̀ ń sìn, kò sì ní bìkítà fún èyí tí àwọn obinrin fẹ́ràn; kò ní bìkítà fún oriṣa kankan, nítorí pé yóo gbé ara rẹ̀ ga ju gbogbo wọn lọ. Dípò gbogbo wọn, yóo máa bọ oriṣa àwọn ìlú olódi; oriṣa tí àwọn baba rẹ̀ kò mọ̀ rí ni yóo máa sìn, yóo máa fún un ní wúrà ati fadaka, òkúta iyebíye ati àwọn ẹ̀bùn olówó iyebíye. Pẹlu ìrànlọ́wọ́ àwọn tí ń bọ oriṣa àjèjì kan, yóo bá àwọn ìlú olódi tí wọ́n lágbára jùlọ jà. Yóo bu ọlá fún àwọn tí wọ́n bá yẹ́ ẹ sí. Yóo fi wọ́n jẹ olórí ọpọlọpọ eniyan; yóo sì fi ilẹ̀ ṣe ẹ̀bùn fún àwọn tí wọ́n bá fún un lówó. “Nígbà tí àkókò ìkẹyìn bá dé, ọba ilẹ̀ Ijipti yóo gbógun tì í; ṣugbọn ọba Siria yóo gbógun tì í bí ìjì líle, pẹlu kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin ati ọpọlọpọ ọkọ̀ ojú omi. Yóo kọlu àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri yóo sì bò wọ́n mọ́lẹ̀ lọ bí àgbàrá òjò. Yóo wọ Ilẹ̀ Ìlérí náà. Ẹgbẹẹgbẹrun yóo ṣubú, ṣugbọn a óo gba Edomu ati Moabu lọ́wọ́ rẹ̀, ati ibi tí ó ṣe pataki jùlọ ninu ilẹ̀ àwọn ará Amoni. Yóo gbógun ti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, Ijipti pàápàá kò ní lè bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Yóo di aláṣẹ lórí wúrà, fadaka ati àwọn nǹkan olówó iyebíye ilẹ̀ Ijipti; àwọn ará Libia ati Etiopia yóo máa tẹ̀lé e lẹ́yìn. Ṣugbọn ìròyìn kan yóo dé láti ìlà oòrùn ati àríwá tí yóo bà á lẹ́rù, yóo sì fi ibinu jáde lọ kọlu ọpọlọpọ, yóo sì pa wọ́n run. Yóo kọ́ ààfin ńlá fún ara rẹ̀ ní ààrin òkun ati ní òkè mímọ́ ológo; sibẹ yóo ṣègbé, kò sì ní sí ẹni tí yóo ràn án lọ́wọ́.” Angẹli tí ó wọ aṣọ funfun náà ní, “Ní àkókò náà Mikaeli, aláṣẹ ńlá, tí ń dáàbò bo àwọn eniyan rẹ, yóo dìde. Àkókò ìyọnu yóo dé, irú èyí tí kò tíì sí rí láti ọjọ́ tí aláyé ti dáyé; ṣugbọn a óo gba gbogbo àwọn eniyan rẹ, tí a bá kọ orúkọ wọn sinu ìwé náà là. Ọ̀pọ̀ ninu àwọn tí ó ti kú, tí wọ́n ti sin ni yóo jí dìde, àwọn kan óo jí sí ìyè ainipẹkun, àwọn mìíràn óo sì jí sí ìtìjú ati ẹ̀sín ainipẹkun. Àwọn ọlọ́gbọ́n yóo máa tàn bí ìmọ́lẹ̀ ojú ọ̀run, àwọn tí wọn ń yí eniyan pada sí ọ̀nà òdodo yóo máa tàn bí ìràwọ̀ lae ati títí lae.” Ó ní, “Ṣugbọn ìwọ Daniẹli, pa ìwé náà dé, kí o sì fi èdìdì dì í títí di àkókò ìkẹyìn. Nítorí àwọn eniyan yóo máa sá síhìn-ín, sá sọ́hùn-ún, ìmọ̀ yóo sì pọ̀ sí i.” Nígbà náà ni mo rí i tí àwọn meji dúró létí bèbè odò kan, ọ̀kan lápá ìhín, ọ̀kan lápá ọ̀hún. Ọ̀kan ninu wọn bi ẹni tí ó wọ aṣọ funfun, tí ó wà lókè odò pé, “Nígbà wo ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń bani lẹ́rù wọnyi yóo dópin?” Ọkunrin tí ó wọ aṣọ funfun, tí ó wà lókè odò na ọwọ́ rẹ̀ mejeeji sókè ọ̀run, mo sì gbọ́ tí ó fi orúkọ ẹni tí ó wà láàyè títí lae búra pé, “Ọdún mẹta ààbọ̀ ni yóo jẹ́. Nígbà tí wọn bá gba agbára lọ́wọ́ àwọn eniyan Ọlọrun patapata, ni gbogbo nǹkan wọnyi yóo ṣẹlẹ̀.” Mo gbọ́ tí ó ń sọ̀rọ̀, ṣugbọn ohun tí ń sọ kò yé mi. Mo bá bèèrè pé, “Olúwa mi, níbo ni nǹkan wọnyi yóo yọrí sí?” Ó dáhùn pé, “Ìwọ Daniẹli, máa bá tìrẹ lọ, nítorí a ti pa ọ̀rọ̀ yìí mọ́, a sì ti fi èdìdì dì í, títí di àkókò ìkẹyìn. Ọ̀pọ̀ eniyan ni yóo wẹ ara wọn mọ́, tí wọn yóo sọ ara wọn di funfun, wọn yóo sì mọ́; ṣugbọn àwọn ẹni ibi yóo máa ṣe ibi; kò ní sí ẹni ibi tí òye yóo yé; ṣugbọn yóo yé àwọn ọlọ́gbọ́n. “Láti ìgbà tí wọn yóo mú ẹbọ ojoojumọ kúrò, tí wọn yóo gbé ohun ìríra sí ibi mímọ́, yóo jẹ́ eedegbeje ọjọ́ ó dín ọjọ́ mẹ́wàá (1,290). Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá forítì í ní gbogbo eedegbeje ọjọ́ ó lé ọjọ́ marundinlogoji (1,335) náà. “Ṣugbọn, ìwọ Daniẹli, máa ṣe tìrẹ lọ títí dé òpin. O óo lọ sí ibi ìsinmi, ṣugbọn lọ́jọ́ ìkẹyìn, o óo dìde nílẹ̀ o óo sì gba ìpín tìrẹ tí a ti fi sílẹ̀ fún ọ.” Ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ fún Hosia, ọmọ Beeri nìyí, ní àkókò tí Usaya ati Jotamu, ati Ahasi, ati Hesekaya jọba ní ilẹ̀ Juda; tí Jeroboamu, ọmọ Joaṣi, sì jọba ní ilẹ̀ Israẹli. Nígbà tí Ọlọrun kọ́kọ́ bá Israẹli sọ̀rọ̀ láti ẹnu Hosia, Ọlọrun ní, “Lọ fẹ́ obinrin alágbèrè kan, kí o sì bí àwọn ọmọ alágbèrè; nítorí pé àwọn eniyan mi ti ṣe àgbèrè pupọ nípa pé, wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀.” Hosia bá lọ fẹ́ iyawo kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gomeri, ọmọ Dibulaimu. Gomeri lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan fún un. OLUWA sọ fún Hosia pé, “Sọ ọmọ náà ní Jesireeli; nítorí láìpẹ́ yìí ni n óo jẹ ìdílé Jehu níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn tí ó dá ní Jesireeli, n óo sì fi òpin sí ìjọba Israẹli. Ní ọjọ́ náà, n óo run àwọn ọmọ ogun Israẹli ní àfonífojì Jesireeli.” Gomeri tún lóyún, ó sì bí ọmọbinrin kan. OLUWA tún sọ fún Hosia pé, “Sọ ọmọ náà ní, ‘Kò sí Àánú’; nítorí n kò ní ṣàánú àwọn eniyan Israẹli mọ́, n kò sì ní dáríjì wọ́n mọ́, ṣugbọn n óo fẹ́ràn ilé Juda, n óo sì ṣàánú wọn, èmi OLUWA Ọlọrun wọn yóo gbà wọ́n là, láìlo ọfà ati ọrun, idà tabi ogun, tabi ẹṣin ati àwọn ẹlẹ́ṣin.” Lẹ́yìn tí Gomeri gba ọmú lẹ́nu ‘Kò sí Àánú’ ó tún lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan. OLUWA tún sọ fún Hosia pé: “Sọ ọmọ náà ní ‘Kì í ṣe Eniyan Mi’, nítorí pé ẹ̀yin ọmọ Israẹli kì í ṣe eniyan mi, èmi náà kì í sì í ṣe Ọlọrun yín.” Àwọn ọmọ Israẹli yóo pọ̀ sí i bí iyanrìn etí òkun tí kò ṣe é wọ̀n, tí kò sì ṣe é kà. Níbi tí a ti sọ fún wọn pé, “Kì í ṣe eniyan mi”, níbẹ̀ ni a óo ti pè wọ́n ní, “ọmọ Ọlọrun Alààyè.” A óo kó àwọn eniyan Israẹli ati ti Juda papọ̀, wọn óo yan olórí kanṣoṣo fún ara wọn; wọn óo sì máa ti ibẹ̀ jáde wá. Dájúdájú, ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ Jesireeli yóo jẹ́. Pe arakunrin rẹ ní “Eniyan mi” kí o sì pe arabinrin rẹ ní “Ẹni tí ó rí àánú gbà.” Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ bá ìyá yín sọ̀rọ̀; nítorí pé kì í ṣe aya mi mọ́, ati pé èmi náà kì í sì í ṣe ọkọ rẹ̀ mọ́. Ẹ sọ fún un pé kí ó má ṣe àgbèrè mọ́, kí ó sì fi ìṣekúṣe rẹ̀ sílẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, n óo tú u sí ìhòòhò, n óo ṣe é bí ìgbà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí i. N óo ṣe é bí aṣálẹ̀, àní, bí ilẹ̀ tí ó gbẹ, n óo sì fi òùngbẹ gbẹ ẹ́ pa. N kò ní ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀, nítorí ọmọ àgbèrè ni wọ́n. Nítorí alágbèrè ni ìyá wọn, ẹni tí ó bí wọn sì ti hùwà ainitiju. Òun fúnrarẹ̀ sọ pé, “N óo sá tẹ̀lé àwọn olólùfẹ́ mi, àwọn tí wọn ń fún mi ní oúnjẹ ati omi, ati aṣọ òtútù, ati aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ funfun, ati òróró olifi ati ọtí.” Nítorí náà, n óo fi ẹ̀gún ṣe ọgbà yí i ká; n óo mọ odi yí i ká, tí kò fi ní rí ọ̀nà jáde. Yóo sá tẹ̀lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, ṣugbọn kò ní lè bá wọn; yóo wá wọn káàkiri pẹlu ìtara, ṣugbọn kò ní rí wọn. Yóo wá wí nígbà náà pé, “N óo pada sọ́dọ̀ ọkọ mi àárọ̀, nítorí ó dára fún mi lọ́dọ̀ rẹ̀ ju ti ìsinsìnyìí lọ.” Kò gbà pé èmi ni mo fún òun ní oúnjẹ, tí mo fún un ní waini ati òróró, tí mo sì fún un ní ọpọlọpọ fadaka ati wúrà tí ó ń lò fún oriṣa Baali. Nítorí náà n óo gba waini ati ọkà mi pada ní àkókò wọn, n óo sì gba aṣọ òtútù ati ẹ̀wù fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ funfun mi, tí kì bá fi bo ìhòòhò rẹ̀. N óo tú u sí ìhòòhò lójú àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, kò sì ní sí ẹni tí yóo lè gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ mi. N óo fi òpin sí ayọ̀ rẹ̀ ati ọjọ́ àsè rẹ̀, ọjọ́ oṣù tuntun rẹ̀, ọjọ́ ìsinmi rẹ̀, ati gbogbo àjọ̀dún tí ó ti yà sọ́tọ̀. N óo run gbogbo igi àjàrà ati igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, àwọn ohun tí ó ń pè ní owó ọ̀yà, tí àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ san fún un. N óo sọ ọgbà rẹ̀ di igbó, àwọn ẹranko ìgbẹ́ yóo sì jẹ wọ́n ní àjẹrun. N óo jẹ ẹ́ níyà fún àwọn ọjọ́ tí ó yà sọ́tọ̀, tí ó fi ń sun turari sí àwọn oriṣa Baali, tí ó kó àwọn ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀ sára, tí ó ń sá tẹ̀lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, tí ó sì gbàgbé mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, n óo tàn án lọ sinu aṣálẹ̀, n óo bá a sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́. N óo sì fún un ní àwọn ọgbà àjàrà rẹ̀ pada níbẹ̀, n óo sì sọ àfonífojì Akori di Ẹnu Ọ̀nà Ìrètí. Yóo kọrin fún mi bí ó tí ń ṣe ní ìgbà èwe rẹ̀, nígbà tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ilẹ̀ Ijipti dé. OLUWA ní, nígbà tí ó bá yá, yóo máa pè mí ní ọkọ rẹ̀, kò ní pè mí ní Baali rẹ̀ mọ́. Nítorí pé, n óo gba orúkọ Baali kúrò lẹ́nu rẹ̀, kò sì ní dárúkọ rẹ̀ mọ́. Nígbà náà ni n óo tìtorí tirẹ̀ bá àwọn ẹranko, àwọn ẹyẹ, ati àwọn nǹkan tí ń fi àyà fà lórí ilẹ̀ dá majẹmu, n óo sì mú ọfà, idà, ati ogun kúrò ní ilẹ̀ náà. N óo jẹ́ kí ẹ máa gbé ní alaafia ati ní àìléwu. Ìwọ Israẹli, n óo sọ ọ́ di iyawo mi títí lae; n óo sọ ọ́ di iyawo mi lódodo ati lótìítọ́, ninu ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati àánú. N óo sọ ọ́ di iyawo mi, lótìítọ́, o óo sì mọ̀ mí ní OLUWA. OLUWA ní, “Ní ọjọ́ náà, n óo dáhùn adura ojú ọ̀run, ojú ọ̀run yó sì dáhùn adura ilẹ̀. Ilẹ̀ yóo sì dáhùn adura ọkà, ati ti waini ati ti òróró. Àwọn náà óo sì dáhùn adura Jesireeli. N óo fi ìdí àwọn eniyan mi múlẹ̀ ní ilẹ̀ náà, wọn yóo sì máa bí sí i. N óo ṣàánú ẹni tí a tí ń pè ní ‘Kò sí àánú’, n óo sì sọ fún ẹni tí a tí ń pè ní ‘Kì í ṣe eniyan mi’ pé eniyan mi ni; òun náà yóo sì dá mi lóhùn pé, ‘Ìwọ ni Ọlọrun mi.’ ” OLUWA tún sọ fún mi pé: “Lọ fẹ́ aya tí ń ṣe àgbèrè pada, kí o fẹ́ràn rẹ̀, bí mo ti fẹ́ràn Israẹli, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n yipada sí ọlọrun mìíràn, wọ́n sì fẹ́ràn láti máa jẹ àkàrà tí ó ní èso resini ninu.” Nítorí náà, mo rà á ní ṣekeli fadaka mẹẹdogun ati ìwọ̀n ọkà baali kan. Mo sì sọ fún un pé, “O gbọdọ̀ wà fún èmi nìkan fún ọjọ́ gbọọrọ láìṣe àgbèrè, láì sì lọ fẹ́ ọkunrin mìíràn; èmi náà yóo sì jẹ́ tìrẹ nìkan.” Nítorí náà, àwọn ọmọ Israẹli yóo wà fún ọjọ́ gbọọrọ láìní ọba tabi olórí láìsí ẹbọ tabi ère, láìsí aṣọ efodu tabi ère terafimu. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Israẹli yóo pada tọ OLUWA Ọlọrun wọn, ati Dafidi, ọba wọn lọ. Wọn yóo fi ìbẹ̀rù wá sọ́dọ̀ OLUWA, wọn yóo sì gba oore rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ̀yin ọmọ Israẹli; OLUWA fi ẹ̀sùn kan gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ Israẹli pé, “Kò sí òtítọ́, tabi àánú, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìmọ̀ Ọlọrun ní ilẹ̀ náà, àfi ìbúra èké ati irọ́ pípa; ìpànìyàn, olè jíjà ati àgbèrè ni ó pọ̀ láàrin wọn. Wọ́n ń yẹ àdéhùn, wọ́n ń paniyan léraléra. Nítorí náà, ilẹ̀ náà ń ṣọ̀fọ̀, gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ibẹ̀ ń jìyà, àwọn ẹranko, àwọn ẹyẹ, ati àwọn ẹja sì ń ṣègbé.” Ọlọrun ní, Kí ẹnikẹ́ni má ṣe jiyàn, ẹ kò sì gbọdọ̀ ka ẹ̀sùn sí ẹnikẹ́ni lẹ́sẹ̀, nítorí pé ẹ̀yin alufaa gan-an ni mò ń fi ẹ̀sùn kàn. Nítorí ẹ óo fẹsẹ̀ kọ lojumọmọ, ẹ̀yin wolii pàápàá yóo kọsẹ̀ lóru, n óo sì pa Israẹli, ìyá yín run. Àwọn eniyan mi ń ṣègbé nítorí àìsí ìmọ̀; nítorí pé ẹ̀yin alufaa ti kọ ìmọ̀ mi sílẹ̀, èmi náà yóo kọ̀ yín ní alufaa mi. Nítorí pé ẹ ti gbàgbé òfin Ọlọrun yín, èmi náà yóo gbàgbé àwọn ọmọ yín. “Bí ẹ̀yin alufaa ti ń pọ̀ sí i, ni ẹ̀ṣẹ̀ yín náà ń pọ̀ sí i, n óo yí ògo wọn pada sí ìtìjú. Ẹ̀ ń fi ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan mi wá oúnjẹ fún ara yín, ẹ sì ń mú kí wọ́n máa dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ Ìyà kan náà ni ẹ̀yin alufaa ati àwọn eniyan yóo jẹ, n óo jẹ yín níyà nítorí ìwà burúkú yín, n óo sì gbẹ̀san lára yín nítorí ìṣe yín. Ẹ óo máa jẹun, ṣugbọn ẹ kò ní yó; Ẹ óo máa ṣe àgbèrè ẹ̀sìn, ṣugbọn ẹ kò ní pọ̀ sí i; nítorí ẹ ti kọ èmi Ọlọrun sílẹ̀ ẹ sì yipada sí ìwà ìbọkúbọ.” OLUWA ní, “Ọtí waini ati waini tuntun ti ra àwọn eniyan mi níyè. Wọ́n ń wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ igi gbígbẹ́, ọ̀pá wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún wọn. Ẹ̀mí àgbèrè ẹ̀sìn ti mú wọn ṣáko, wọ́n ti kọ Ọlọrun wọn sílẹ̀ láti máa bọ ìbọkúbọ. Wọ́n ń rúbọ lórí òkè gíga, wọ́n ń sun turari lórí òkè kéékèèké, ati lábẹ́ igi oaku, ati igi populari ati igi terebinti, nítorí òjìji abẹ́ wọn tutù. Nítorí náà ni àwọn ọmọbinrin yín ṣe di aṣẹ́wó, àwọn aya yín sì di alágbèrè. Ṣugbọn n kò ní jẹ àwọn ọmọbinrin yín níyà nígbà tí wọ́n bá ń ṣe aṣẹ́wó, tabi kí n jẹ àwọn aya yín níyà nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrè; nítorí pé, àwọn ọkunrin yín pàápàá ń bá àwọn aṣẹ́wó lòpọ̀, wọ́n sì ń bá àwọn aṣẹ́wó ilé oriṣa rúbọ. Àwọn tí wọn kò bá ní ìmọ̀ yóo sì parun. “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ò ń ṣe àgbèrè ẹ̀sìn, ìwọ Israẹli, má kó ẹ̀bi bá Juda. Má wọ Giligali lọ bọ̀rìṣà, má sì gòkè lọ sí Betafeni, má sì lọ búra níbẹ̀ pé, ‘Bí OLUWA tí ń bẹ.’ Israẹli ń ṣe agídí bí ọ̀dọ́ mààlúù tí ó ya olóríkunkun; ṣe OLUWA lè máa bọ́ wọn bí aguntan nisinsinyii lórí pápá tí ó tẹ́jú. Ìbọ̀rìṣà ti wọ Efuraimu lẹ́wù, ẹ fi wọ́n sílẹ̀. Ẹgbẹ́ ọ̀mùtí ni wọ́n, wọ́n fi ara wọn fún ìwà àgbèrè, ìtìjú yá wọn lára ju ògo lọ. Afẹ́fẹ́ yóo gbá wọn lọ, ojú ìsìn ìbọ̀rìṣà wọn yóo sì tì wọ́n. “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin alufaa! Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ Israẹli ati ẹ̀yin ìdílé ọba! Ẹ̀yin ni ìdájọ́ náà dé bá; nítorí ẹ dàbí tàkúté ní Misipa, ati bí àwọ̀n tí a ta sílẹ̀ lórí òkè Tabori. Wọ́n ti gbẹ́ kòtò jíjìn ní ìlú Ṣitimu; ṣugbọn n óo jẹ wọ́n níyà. Mo mọ Efuraimu, bẹ́ẹ̀ ni Israẹli kò ṣàjèjì sí mi; nisinsinyii, ìwọ Efuraimu ti ṣe àgbèrè ẹ̀sìn, Israẹli sì ti di aláìmọ́.” Gbogbo ibi tí wọn ń ṣe, kò jẹ́ kí wọ́n lè pada sọ́dọ̀ Ọlọrun wọn, nítorí pé ọkàn wọn kún fún ẹ̀mí àgbèrè, wọn kò sì mọ OLUWA. Ìgbéraga Israẹli hàn kedere lójú rẹ̀; Efuraimu yóo kọsẹ̀, yóo sì ṣubú ninu ìwà burúkú rẹ̀, Juda náà yóo ṣubú pẹlu wọn. Wọn yóo mú mààlúù ati aguntan wá, láti fi wá ojurere OLUWA, ṣugbọn wọn kò ní rí i; nítorí pé, ó ti fi ara pamọ́ fún wọn. Wọ́n ti hùwà aiṣootọ sí OLUWA; nítorí pé wọ́n ti bí ọmọ àjèjì. Oṣù tuntun ni yóo run àtàwọn, àtoko wọn. Ẹ fọn fèrè ní Gibea, ẹ fọn fèrè ogun ní Rama, ẹ pariwo ogun ní Betafeni, ogun dé o, ẹ̀yin ará Bẹnjamini! Efuraimu yóo di ahoro ní ọjọ́ ìjìyà; mo ti fi ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ dájúdájú hàn, láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli. OLUWA wí pé: “Àwọn olórí ní Juda dàbí àwọn tí wọn ń yí ààlà ilẹ̀ pada, n óo da ibinu mi sórí wọn, bí ẹni da omi. Ìyà ń jẹ Efuraimu, ìdájọ́ ìparun sì ti dé bá a, nítorí pé, ó ti pinnu láti máa tẹ̀lé ohun asán. Nítorí náà, mo dàbí kòkòrò ajẹnirun sí Efuraimu, ati bí ìdíbàjẹ́ sí Juda. “Nígbà tí Efuraimu rí àìsàn rẹ̀, tí Juda sì rí ọgbẹ́ rẹ̀, Efuraimu sá tọ Asiria lọ, ó sì ranṣẹ sí ọba ńlá ibẹ̀. Ṣugbọn kò lè wo àìsàn Israẹli tabi kí ó wo ọgbẹ́ rẹ̀ sàn. Bíi kinniun ni n óo rí sí Efuraimu, n óo sì fò mọ́ Juda bí ọ̀dọ́ kinniun. Èmi fúnra mi ni n óo fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, n óo sì kúrò níbẹ̀. N óo kó wọn lọ, kò sì ní sí ẹni tí yóo lè gbà wọ́n sílẹ̀. “N óo pada sí ibùgbé mi títí wọn yóo fi mọ ẹ̀bi wọn, tí wọn yóo sì máa wá mi nígbà tí ojú bá pọ́n wọn.” Wọn óo wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á pada sọ́dọ̀ OLUWA; nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti fà wá ya, sibẹ yóo wò wá sàn; ó ti pa wá lára lóòótọ́, ṣugbọn yóo di ọgbẹ́ wa. Lẹ́yìn ọjọ́ meji, yóo sọ wá jí, ní ọjọ́ kẹta, yóo gbé wa dìde, kí á lè wà láàyè níwájú rẹ̀. Ẹ jẹ́ kí á mọ̀ ọ́n, ẹ jẹ́ kí á tẹ̀síwájú kí á mọ OLUWA. Dídé rẹ̀ dájú bí àfẹ̀mọ́jú; yóo sì pada wá sọ́dọ̀ wa bí ọ̀wààrà òjò, ati bí àkọ́rọ̀ òjò tí ń bomirin ilẹ̀.” Ṣugbọn OLUWA wí pé, “Kí ni kí n ti ṣe ọ́ sí, ìwọ Efuraimu? Kí ni kí n ti ṣe ọ́ sí, ìwọ Juda? Ìfẹ́ yín dàbí ìkùukùu òwúrọ̀, ati bí ìrì tíí yára á gbẹ. Nítorí náà ni mo fi jẹ́ kí àwọn wolii mi ké wọn lulẹ̀, mo ti fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi pa wọ́n, ìdájọ́ mi sì yọ bí ìmọ́lẹ̀. Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ rírú; ìmọ̀ Ọlọrun ni mo bèèrè, kì í ṣe ẹbọ sísun. “Ṣugbọn wọ́n yẹ àdéhùn tí mo bá wọn ṣe, bí Adamu, wọ́n hùwà aiṣododo sí èmi Ọlọrun. Gileadi ti di ìlú àwọn ẹni ibi, ó kún fún ìpànìyàn. Bí àwọn ọlọ́ṣà tií ba de eniyan, bẹ́ẹ̀ ni àwọn alufaa kó ara wọn jọ, láti paniyan ní ọ̀nà Ṣekemu, wọ́n ń ṣe nǹkan ìtìjú láìbìkítà. Mo rí ohun tí ó burú gan-an ní Israẹli; ìbọ̀rìṣà Efuraimu wà níbẹ̀, Israẹli sì ti ba ara wọn jẹ́. “Ẹ̀yin ará Juda pàápàá, mo ti dá ọjọ́ ìjìyà yín sọ́nà, fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ̀ ń dá. “Nígbà tí mo bá fẹ́ dá ire Israẹli eniyan mi pada, tí mo bá sì fẹ́ wò wọ́n sàn, kìkì ìwà ìbàjẹ́ Efuraimu ati ìwà ìkà Samaria ni mò ń rí; nítorí pé ìwà aiṣododo ni wọ́n ń hù. Àwọn olè ń fọ́lé, àwọn jàgùdà sì ń jalè ní ìgboro. Ṣugbọn wọn kò rò ó pé mò ń ranti gbogbo ìwà burúkú àwọn. Ìwà burúkú wọn yí wọn ká, ẹ̀ṣẹ̀ wọn sì wà níwájú mi.” OLUWA wí pé, “Àwọn eniyan ń dá ọba ninu dùn, nípa ìwà ibi wọn, wọ́n ń mú àwọn ìjòyè lóríyá nípa ìwà ẹ̀tàn wọn. Alágbèrè ni gbogbo wọn; wọ́n dàbí iná ààrò burẹdi tí ó gbóná, tí ẹni tí ń ṣe burẹdi kò koná mọ́, láti ìgbà tí ó ti po ìyẹ̀fun títí tí ìyẹ̀fun náà fi wú. Ní ọjọ́ tí ọba ń ṣe àjọyọ̀, àwọn ìjòyè mu ọtí àmupara, títí tí ara wọn fi gbóná; ọba pàápàá darapọ̀ mọ́ àwọn ẹlẹ́yà. Iná ọ̀tẹ̀ wọn ń jò bí iná ojú ààrò, inú wọn ń ru, ó ń jó bí iná ní gbogbo òru; ní òwúrọ̀, ó ń jó lálá bí ahọ́n iná. “Gbogbo wọn gbóná bí ààrò, wọ́n pa àwọn olórí wọn, gbogbo ọba wọn ni wọ́n ti pa léraléra, kò sì sí ẹnìkan ninu wọn tí ó ké pè mí.” OLUWA ní, “Efuraimu darapọ̀ mọ́ àwọn eniyan tí wọ́n yí wọn ká, Efuraimu dàbí àkàrà tí kò jinná dénú. Àwọn àjèjì ti gba agbára rẹ̀, sibẹsibẹ kò mọ̀; orí rẹ̀ kún fún ewú, sibẹsibẹ kò mọ̀. Ìgbéraga àwọn ọmọ Israẹli ń takò wọ́n, sibẹsibẹ wọn kò pada sọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun wọn, tabi kí wọ́n tilẹ̀ wá a nítorí gbogbo ohun tí wọ́n ti ṣe. Efuraimu dàbí ẹyẹ àdàbà, ó jẹ́ òmùgọ̀ ati aláìlóye, ó ń pe Ijipti fún ìrànlọ́wọ́, o ń sá tọ Asiria lọ. Ṣugbọn bí wọn tí ń lọ, n óo da àwọ̀n lé wọn lórí, n óo mú wọn bí ẹyẹ ojú ọ̀run; n óo sì jẹ wọ́n níyà fún ìwà burúkú wọn. “Wọ́n gbé, nítorí pé wọ́n ti ṣáko kúrò lọ́dọ̀ mi! Ìparun yóo kọlù wọ́n, nítorí pé wọ́n ń bá mi ṣọ̀tẹ̀! Ǹ bá rà wọ́n pada, ṣugbọn wọ́n ń parọ́ mọ́ mi. Wọ́n ń sọkún lórí ibùsùn wọn, ṣugbọn ẹkún tí wọn ń sun sí mi kò ti ọkàn wá; nítorí oúnjẹ ati ọtí waini ni wọ́n ṣe ń gbé ara ṣánlẹ̀; ọ̀tẹ̀ ni wọ́n ń bá mi ṣe. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, èmi ni mo tọ́ wọn dàgbà, tí mo sì fún wọn lókun, sibẹsibẹ wọ́n ń gbèrò ibi sí mi. Wọ́n yipada sí oriṣa Baali, wọ́n dàbí ọrun tí ó wọ́, idà ni a óo fi pa àwọn olórí wọn, nítorí ìsọkúsọ ẹnu wọn. Nítorí náà, wọn óo ṣẹ̀sín ní ilẹ̀ Ijipti.” OLUWA ní: “Ẹ ti fèrè bọnu, nítorí ẹyẹ igún wà lórí ilé mi, nítorí pé wọ́n ti yẹ àdéhùn tí mo bá wọn ṣe, wọ́n sì ti rú òfin mi. Wọ́n ń ké pè mí, wọ́n ń wí pé, ‘Ọlọrun wa, àwa ọmọ Israẹli mọ̀ ọ́.’ Israẹli ti kọ ohun rere sílẹ̀; nítorí náà, àwọn ọ̀tá yóo máa lépa wọn. “Wọ́n ń fi ọba jẹ, láìsí àṣẹ mi. Wọ́n ń yan àwọn aláṣẹ, ṣugbọn n kò mọ̀ nípa rẹ̀. Wọ́n ń fi fadaka ati wúrà wọn yá ère fún ìparun ara wọn. Mo kọ oriṣa ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù yín, ẹ̀yin ará Samaria. Inú mi ń ru sí wọn. Yóo ti pẹ́ tó kí àwọn ọmọ Israẹli tó di mímọ́? Oriṣa ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù kì í ṣe Ọlọrun, iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni, a óo sì rún ti Samaria wómúwómú. Wọ́n ń gbin afẹ́fẹ́, wọn yóo sì ká ìjì líle. Ọkà tí kò bá tú, kò lè lọ́mọ, bí wọ́n bá tilẹ̀ lọ́mọ, tí wọ́n sì gbó, àwọn àjèjì ni yóo jẹ ẹ́ run. A ti tú Israẹli ká, wọ́n ti kọ́ àṣàkaṣà àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà láàrin wọn, wọ́n sì dàbí ohun èlò tí kò wúlò. Nítorí pé wọ́n lọ sí Asiria, wọ́n dàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́ tí ń dá rìn; Efuraimu ti bẹ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lọ́wẹ̀ fún ààbò. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ta ara wọn fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, n óo kó wọn jọ láìpẹ́, láti jẹ wọ́n níyà, fún ìgbà díẹ̀, lọ́dọ̀ àwọn ọba alágbára tí yóo ni wọ́n lára. “Nítorí Efuraimu ti tẹ́ ọpọlọpọ pẹpẹ láti dẹ́ṣẹ̀ níbẹ̀, wọ́n ti di pẹpẹ ẹ̀ṣẹ̀ dídá fún un. Bí mo tilẹ̀ kọ òfin mi sílẹ̀ ní ìgbà ẹgbẹrun, sibẹsibẹ wọn óo kà wọ́n sí nǹkan tó ṣàjèjì. Wọ́n fẹ́ràn ati máa rúbọ; wọ́n ń fi ẹran rúbọ, wọ́n sì ń jẹ ẹ́; ṣugbọn inú OLUWA kò dùn sí wọn. Yóo wá ranti àìdára wọn nisinsinyii, yóo sì jẹ wọ́n níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn; wọn óo sì pada sí Ijipti. “Àwọn ọmọ Israẹli ti gbàgbé Ẹlẹ́dàá wọn, wọ́n sì ti kọ́ ààfin fún ara wọn. Àwọn ọmọ Juda ti kọ́ ọpọlọpọ ìlú olódi sí i; ṣugbọn n óo sọ iná sí àwọn ìlú wọn, yóo sì jó àwọn ibi ààbò wọn ní àjórun.” Ẹ̀yin ọmọ Israẹli ẹ má yọ̀, ẹ sì má dá ara yín ninu dùn, bí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, nítorí ẹ ti kọ Ọlọrun yín sílẹ̀, ẹ ti ṣe àgbèrè ẹ̀sìn lọ sọ́dọ̀ oriṣa. Inú yín ń dùn sí owó iṣẹ́ àgbèrè ní gbogbo ibi ìpakà yín. Ọkà ibi ìpakà yín ati ọtí ibi ìpọntí yín kò ní to yín, kò sì ní sí waini tuntun mọ́. Àwọn ọmọ Israẹli kò ní dúró ní ilẹ̀ OLUWA mọ́; Efuraimu yóo pada sí Ijipti, wọn yóo sì jẹ ohun àìmọ́ ní ilẹ̀ Asiria. Wọn kò ní rú ẹbọ ohun mímu sí OLUWA, bẹ́ẹ̀ ni ẹbọ wọn kò ní tẹ́ ẹ lọ́rùn. Oúnjẹ wọn yóo dàbí oúnjẹ àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, àwọn tí wọ́n bá jẹ ninu rẹ̀ yóo di aláìmọ́. Ebi nìkan ni oúnjẹ wọn yóo wà fún, wọn kò ní mú wá fi rúbọ lára rẹ̀ ní ilé OLUWA. Kí ni wọn óo ṣe ní ọjọ́ àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀, kí ni wọn óo ṣe ní ọjọ́ àsè OLUWA? Wọn yóo fọ́nká lọ sí Asiria; Ijipti ni yóo gbá wọn jọ, Memfisi ni wọn yóo sin wọ́n sí, Ẹ̀gún ọ̀gàn ni yóo hù bo àwọn nǹkan èlò fadaka olówó iyebíye wọn, ẹ̀gún yóo sì hù ninu àgọ́ wọn. Àkókò ìjìyà ati ẹ̀san ti dé, Israẹli yóo sì mọ̀. Ẹ̀ ń wí pé, “Òmùgọ̀ ni wolii, aṣiwèrè sì ni ẹni tí ó wà ninu ẹ̀mí,” nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá yín, ati ìkórìíra yín tí ó pọ̀. Wolii ni aṣọ́nà fún Efuraimu, àwọn eniyan Ọlọrun mi, sibẹsibẹ tàkúté àwọn pẹyẹpẹyẹ wà lójú gbogbo ọ̀nà rẹ̀, ìkórìíra sì wà ní ilé Ọlọrun rẹ̀. Wọ́n ti sọ ara wọn di aláìmọ́ lọpọlọpọ, bí ìgbà tí wọ́n wà ní Gibea. Ọlọrun yóo ranti àìdára tí wọ́n ṣe, yóo sì jẹ wọ́n níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. OLUWA wí pé: “Mo rí Israẹli he bí ìgbà tí eniyan rí èso àjàrà he ninu aṣálẹ̀. Lójú mi, àwọn baba ńlá yín dàbí èso tí igi ọ̀pọ̀tọ́ kọ́ so ní àkókò àkọ́so rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n rí sí mi, ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé òkè Baali Peori, wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ fún oriṣa Baali, wọ́n sì di ohun ẹ̀gbin, bí oriṣa tí wọ́n fẹ́ràn. Ògo Efuraimu yóo fò lọ bí ẹyẹ, wọn kò ní lóyún, wọn kò ní bímọ, bẹ́ẹ̀ ni ọlẹ̀ kò ní sọ ninu wọn! Bí wọ́n bá tilẹ̀ bímọ, n óo pa wọ́n tí kò ní ku ẹyọ kan. Bí mo bá kọ̀ wọ́n sílẹ̀, wọ́n gbé!” Mo rí àwọn ọmọ Efuraimu bí ẹran àpajẹ; Efuraimu gbọdọ̀ kó àwọn ọmọ rẹ̀ jáde fún pípa. Fún wọn ní nǹkankan, OLUWA, OLUWA, kí ni ò bá tilẹ̀ fún wọn? Jẹ́ kí oyún máa bàjẹ́ lára obinrin wọn, kí ọmú wọn sì gbẹ. OLUWA ní, “Gbogbo ìwà burúkú wọn wà ní Giligali, ibẹ̀ ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí kórìíra wọn. Nítorí iṣẹ́ burúkú wọn, n óo lé wọn jáde ní ilé mi. N kò ní fẹ́ràn wọn mọ́, ọlọ̀tẹ̀ ni gbogbo àwọn olórí wọn. Ìyà jẹ Efuraimu, gbòǹgbò wọn ti gbẹ, wọn kò sì ní so èso mọ́. Bí wọ́n tilẹ̀ bímọ, n óo pa àwọn ọmọ tí wọ́n fẹ́ràn.” Ọlọrun mi yóo pa wọ́n run, nítorí pé wọn kò fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀; wọn yóo di alárìnkiri láàrin àwọn orílẹ̀-èdè. Àwọn ọmọ Israẹli dàbí àjàrà dáradára tí ń so èso pupọ. Bí èso rẹ̀ tí ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni pẹpẹ oriṣa wọn ń pọ̀ sí i. Bí àwọn ìlú wọn tí ń dára sí i ni àwọn ọ̀wọ̀n oriṣa wọn náà ń dára sí i. Èké ni wọ́n, nítorí náà wọn óo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, OLUWA yóo wó pẹpẹ wọn lulẹ̀, yóo sì fọ́ àwọn ọ̀wọ̀n oriṣa wọn. Wọn óo máa wí nisinsinyii pé, “A kò ní ọba, nítorí pé a kò bẹ̀rù OLUWA; kí ni ọba kan fẹ́ ṣe fún wa?” Wọ́n ń fọ́nnu lásán; wọ́n ń fi ìbúra asán dá majẹmu; nítorí náà ni ìdájọ́ ṣe dìde sí wọn bíi koríko olóró, ní poro oko. Àwọn ará Samaria wárìrì fún ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù, oriṣa ìlú Betafeni. Àwọn eniyan ibẹ̀ yóo ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, àwọn babalóòṣà rẹ̀ yóo pohùnréré ẹkún lé e lórí, nítorí ògo rẹ̀ tí ó ti fò lọ. Dájúdájú, a óo gbé ère oriṣa náà lọ sí Asiria, a óo fi ṣe owó ìṣákọ́lẹ̀ fún ọba ńlá ibẹ̀. Ojú yóo ti Efuraimu, ojú yóo sì ti Israẹli nítorí ère oriṣa rẹ̀. Ọba Samaria yóo parun bí ẹ̀ẹ́rún igi tí ó léfòó lórí omi. A óo pa ibi pẹpẹ ìrúbọ Afeni, tíí ṣe ẹ̀ṣẹ̀ fún Israẹli run; ẹ̀gún ati òṣùṣú yóo hù jáde lórí àwọn pẹpẹ wọn. Wọn yóo sì sọ fún àwọn òkè gíga pé kí wọ́n bo àwọn mọ́lẹ̀, wọn óo sì sọ fún àwọn òkè kéékèèké pé kí wọ́n wó lu àwọn. Láti ìgbà Gibea ni Israẹli ti ń dẹ́ṣẹ̀; sibẹ wọn kò tíì jáwọ́ ninu ẹ̀ṣẹ̀. Ṣé ogun kò ní pa wọ́n ní Gibea? N óo dojú kọ àwọn tí ń ṣe ségesège n óo jẹ wọ́n níyà. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo parapọ̀ láti kojú wọn, nígbà tí wọ́n bá ń jìyà fún ọpọlọpọ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Efuraimu dàbí ọmọ mààlúù tí a ti fi iṣẹ́ ṣíṣe kọ́, tí ó sì fẹ́ràn láti máa pa ọkà, mo fi ọrùn rẹ̀ tí ó lẹ́wà sílẹ̀; ṣugbọn nisinsinyii, n óo gbé àjàgà bọ̀ ọ́ lọ́rùn, ó di dandan kí Juda kọ ilẹ̀, kí Israẹli sì máa ro oko fún ara rẹ̀. Ẹ gbin òdodo fún ara yín, kí ẹ sì ká èso ìfẹ́ tí kì í yẹ̀; ẹ lọ dá oko sí ilẹ̀ tí ẹ ti kọ̀ sílẹ̀, nítorí ó tó àkókò láti wá OLUWA, kí ó lè wá rọ ìgbàlà le yín lórí bí òjò. Ẹ ti gbin ẹ̀ṣẹ̀, ẹ sì ti ká aiṣododo, ẹ ti jẹ èso ẹ̀tàn. “Nítorí pé ẹ gbẹ́kẹ̀lé kẹ̀kẹ́ ogun ati ọpọlọpọ ọmọ ogun yín, nítorí náà, ogun yóo bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn eniyan yín, gbogbo ibi ààbò yín ni yóo parun. Bí Ṣalimani ti pa Betabeli run, ní ọjọ́ ogun, ní ọjọ́ tí wọ́n pa ìyá tòun tọmọ; bẹ́ẹ̀ ni a óo ṣe si yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, nítorí ìwà burúkú yín. Bí ogun bá tí ń bẹ̀rẹ̀ ni a óo ti pa ọba Israẹli run.” OLUWA ní, “Nígbà tí Israẹli wà ní ọmọde, mo fẹ́ràn rẹ̀, láti ilẹ̀ Ijipti ni mo sì ti pe ọmọ mi jáde. Ṣugbọn bí mo ti ń pè wọ́n tó, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ń sá fún mi, wọ́n ń rúbọ sí àwọn oriṣa Baali, wọ́n ń sun turari sí ère. Bẹ́ẹ̀ ni èmi ni mo kọ́ Efuraimu ní ìrìn, mo gbé wọn lé ọwọ́ mi, ṣugbọn wọn kò mọ̀ pé èmi ni mo wo àwọn sàn. Mo fà wọ́n mọ́ra pẹlu okùn àánú ati ìdè ìfẹ́, mo dàbí ẹni tí ó tú àjàgà kúrò ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ wọn, mo sì bẹ̀rẹ̀, mo gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú wọn. “Wọn óo pada sí ilẹ̀ Ijipti, Asiria óo sì jọba lé wọn lórí, nítorí pé wọ́n kọ̀, wọn kò pada sọ́dọ̀ mi. A óo fi idà run àwọn ìlú wọn, irin ìdábùú ìlẹ̀kùn bodè wọn yóo ṣẹ́, a óo sì pa wọ́n run ninu ibi ààbò wọn. Àwọn eniyan mi ti pinnu láti yipada kúrò lọ́dọ̀ mi, nítorí náà n óo ti àjàgà bọ̀ wọ́n lọ́rùn, kò sì ní sí ẹni tí yóo bá wọn bọ́ ọ. “Mo ha gbọdọ̀ yọwọ́ lọ́rọ̀ yín ẹ̀yin Efuraimu? Mo ha gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀, Israẹli? Mo ha gbọdọ̀ pa ọ́ run bí mo ti pa Adimai run; kí n ṣe sí ọ bí mo ti ṣe sí Seboimu? Ọkàn mi kò gbà á, àánú yín a máa ṣe mí. N kò ní fa ibinu yọ mọ́, n kò ní pa Efuraimu run mọ́, nítorí pé Ọlọrun ni mí, n kì í ṣe eniyan, èmi ni Ẹni Mímọ́ tí ó wà láàrin yín, n kò sì ní pa yín run. “Àwọn ọmọ Israẹli yóo wá mi, n óo sì bú bíi kinniun; lóòótọ́ n óo bú, àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin yóo sì fi ìbẹ̀rùbojo jáde wá láti ìwọ̀ oòrùn; wọn yóo fi ìbẹ̀rùbojo fò wá bí ẹyẹ láti ilẹ̀ Ijipti, ati bí ẹyẹ àdàbà láti ilẹ̀ Asiria; n óo sì dá wọn pada sí ilé wọn. Èmi OLUWA ni mo wí bẹ́ẹ̀.” OLUWA ní, “Àwọn ọmọ Efuraimu parọ́ fún mi, ilẹ̀ Israẹli kún fún ẹ̀tàn, sibẹsibẹ mo mọ ilé Juda, nítorí pé ó jẹ́ olóòótọ́ sí èmi, Ẹni Mímọ́. “Asán ati ìbàjẹ́ ni gbogbo nǹkan tí Efuraimu ń ṣe látàárọ̀ dalẹ́. Wọ́n ń parọ́ kún irọ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwà ipá wọn ń pọ̀ sí i. Wọ́n ń bá àwọn Asiria dá majẹmu, wọ́n sì ń ru òróró lọ sí ilẹ̀ Ijipti.” OLUWA ní ẹjọ́ tí yóo bá àwọn ọmọ Juda rò, yóo jẹ àwọn ọmọ Israẹli níyà gẹ́gẹ́ bí ìwà wọn, yóo sì san ẹ̀san iṣẹ́ ọwọ́ wọn fún wọn. Jakọbu, baba ńlá wọn di arakunrin rẹ̀ ní gìgísẹ̀ mú ninu oyún, nígbà tí ó dàgbà tán, ó bá Ọlọrun wọ̀jàkadì. Ó bá angẹli jà, ó ja àjàṣẹ́gun, ó sọkún, ó sì wá ojurere rẹ̀. Ó bá Ọlọrun pàdé ní Bẹtẹli, níbẹ̀ ni Ọlọrun sì ti bá a sọ̀rọ̀. OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, OLUWA ni orúkọ rẹ̀: Nítorí náà, ẹ yipada nípa agbára Ọlọrun yín, ẹ di ìfẹ́ ati ìdájọ́ òdodo mú, kí ẹ sì dúró de Ọlọrun yín nígbà gbogbo. OLUWA ní, “Efuraimu jẹ́ oníṣòwò tí ó gbé òṣùnwọ̀n èké lọ́wọ́, ó sì fẹ́ràn láti máa ni eniyan lára. Efuraimu ní, ‘Mo ní ọrọ̀, mo ti kó ọrọ̀ jọ fún ara mi, ṣugbọn gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ kò lè mú ẹ̀bi rẹ̀ kúrò.’ Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ láti ilẹ̀ Ijipti; n óo tún mú ọ pada gbé inú àgọ́, bí àwọn ọjọ́ àjọ ìyàsọ́tọ̀. “Mo bá àwọn wolii sọ̀rọ̀; èmi ni mo fi ọpọlọpọ ìran hàn wọ́n, tí mo sì tipasẹ̀ wọn pa ọpọlọpọ òwe. Ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà wà ní Gileadi, dájúdájú yóo parun; bí wọ́n bá fi akọ mààlúù rúbọ ní Giligali, pẹpẹ wọn yóo dàbí òkúta tí a kójọ ní poro oko.” Jakọbu sálọ sí ilẹ̀ Aramu, níbẹ̀ ni ó ti singbà, tí ó ṣiṣẹ́ darandaran, nítorí iyawo tí ó fẹ́. Nípasẹ̀ wolii kan ni OLUWA ti mú Israẹli jáde kúrò ní Ijipti, nípasẹ̀ wolii kan ni a sì ti pa á mọ́. Efuraimu ti mú èmi, OLUWA rẹ̀ bínú lọpọlọpọ, nítorí náà, n óo da ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ lé e lórí, òun tí ó gàn mí ni yóo di ẹni ẹ̀gàn. Tẹ́lẹ̀ rí, bí ẹ̀yà Efuraimu bá sọ̀rọ̀, àwọn eniyan a máa wárìrì; wọ́n níyì láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli yòókù, ṣugbọn nítorí pé wọ́n bọ oriṣa Baali, wọ́n dẹ́ṣẹ̀, wọ́n sì kú. Nisinsinyii, wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n yá ère fún ara wọn; ère fadaka, iṣẹ́ ọwọ́ eniyan, Wọ́n ń sọ pé, “Ẹ wá rúbọ sí i.” Eniyan wá ń fi ẹnu ko ère mààlúù lẹ́nu! Nítorí náà, wọn óo dàbí ìkùukùu òwúrọ̀, ati bí ìrì tíí máa ń yára gbẹ, wọ́n óo dàbí ìyàngbò tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kúrò ní ibi ìpakà, ati bí èéfín tí ń jáde láti ojú fèrèsé. OLUWA ní, “Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, láti ìgbà tí ẹ ti wà ní ilẹ̀ Ijipti: ẹ kò ní Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn mi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì ní olùgbàlà mìíràn lẹ́yìn mi. Èmi ni mo ṣe ìtọ́jú yín nígbà tí ẹ wà ninu aṣálẹ̀, ninu ilẹ̀ gbígbẹ; ṣugbọn nígbà tí ẹ jẹun yó tán, ẹ̀ ń gbéraga, ẹ gbàgbé mi. Nítorí náà, bíi kinniun ni n óo ṣe si yín, n óo lúgọ lẹ́bàá ọ̀nà bí àmọ̀tẹ́kùn; n óo yọ si yín bí ẹranko beari tí wọ́n kó lọ́mọ lọ, n óo sì fa àyà yín ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. N óo ya yín jẹ bíi kinniun, bí ẹranko burúkú ṣe ń fa ẹran ya. “N óo pa yín run, ẹ̀yin ọmọ Israẹli; ta ni yóo ràn yín lọ́wọ́? Níbo ni ọba yín wà nisinsinyii, tí yóo gbà yín là? Níbo ni àwọn olórí yín wà, tí wọn yóo gbèjà yín? Àwọn tí ẹ bèèrè fún, tí ẹ ní, ‘Ẹ fún wa ní ọba ati àwọn ìjòyè.’ Pẹlu ibinu, ni mo fi fun yín ní àwọn ọba yín, ìrúnú ni mo sì fi mú wọn kúrò. “A ti di ẹ̀ṣẹ̀ Efuraimu ní ìtí ìtí, a ti kó ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ pamọ́. Àwọn ọmọ Israẹli ní anfaani láti wà láàyè, ṣugbọn ìwà òmùgọ̀ wọn kò jẹ́ kí wọ́n lo anfaani náà. Ó dàbí ọmọ tí ó kọ̀, tí kò jáde kúrò ninu ìyá rẹ̀ ní àkókò ìrọbí. N kò ní rà wọ́n pada kúrò lọ́wọ́ agbára isà òkú, n kò ní rà wọ́n pada kúrò lọ́wọ́ ikú. Ikú! Níbo ni àjàkálẹ̀ àrùn rẹ wà? Ìwọ isà òkú! Ìparun rẹ dà? Àánú kò sí lójú mi mọ́. Bí Israẹli tilẹ̀ rúwé bí ewéko etí odò, atẹ́gùn OLUWA láti ìlà oòrùn yóo fẹ́ wá, yóo wá láti inú aṣálẹ̀; orísun rẹ̀ yóo gbẹ, ojú odò rẹ̀ yóo sì gbẹ pẹlu; a óo kó ìṣúra ati ohun èlò olówó iyebíye rẹ̀ kúrò. Samaria ni yóo ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, nítorí ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí èmi Ọlọrun rẹ̀, ogun ni yóo pa wọ́n, a óo ṣán àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀, a óo sì la inú àwọn aboyún wọn.” Ẹ pada tọ OLUWA Ọlọrun yín lọ, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, nítorí pé ẹ ti kọsẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín. Ẹ pada sọ́dọ̀ OLUWA, kí ẹ sọ pé, “Mú ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò, gba ohun tí ó dára a óo sì máa yìn ọ́ lógo. Asiria kò lè gbà wá là, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní gun ẹṣin; a kò sì ní pe oriṣa, tíí ṣe iṣẹ́ ọwọ́ wa, ní Ọlọrun wa mọ́. OLUWA, ìwọ ni ò ń ṣàánú fún ọmọ tí kò lẹ́nìkan.” Ọlọrun ní, “N óo gba ìwà aiṣootọ lọ́wọ́ wọn, n óo fẹ́ wọn tọkàntọkàn, nítorí n kò bínú sí wọn mọ́. Bí ìrì ni n óo máa sẹ̀ sí Israẹli, ẹwà rẹ̀ yóo yọ bí òdòdó lílì, gbòǹgbò rẹ̀ yóo sì múlẹ̀ bíi gbòǹgbò igi kedari Lẹbanoni. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóo tàn kálẹ̀; ẹwà rẹ̀ yóo yọ bíi ti igi olifi, òórùn rẹ̀ yóo sì dàbí ti igi Lẹbanoni. Wọn óo pada sábẹ́ ààbò mi, wọn óo rúwé bí igi inú ọgbà; wọn óo sì tanná bí àjàrà, òórùn wọn óo dàbí ti waini Lẹbanoni. Efuraimu yóo sọ pé, ‘kí ni mo ní ṣe pẹlu àwọn oriṣa?’ Nítorí èmi ni n óo máa gbọ́ adura rẹ̀, tí n óo sì máa tọ́jú rẹ̀. Mo dàbí igi sipirẹsi tí kì í wọ́wé tòjò tẹ̀ẹ̀rùn. Lọ́dọ̀ mi ni èso rẹ̀ ti ń wá.” Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́n, kí ó mọ àwọn nǹkan wọnyi; kí òye rẹ̀ sì yé ẹnikẹ́ni tí ó bá lóye; nítorí pé ọ̀nà OLUWA tọ́, àwọn tí wọ́n bá dúró ṣinṣin ni yóo máa tọ̀ ọ́, ṣugbọn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo kọsẹ̀ níbẹ̀. Iṣẹ́ tí OLUWA rán Joẹli, ọmọ Petueli nìyí: Ẹ gbọ́, ẹ̀yin àgbà, ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ yìí! Ǹjẹ́ irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹlẹ̀ rí ní àkókò yín, tabi ní àkókò àwọn baba yín? Ẹ sọ fún àwọn ọmọ yín nípa rẹ̀, kí àwọn náà sọ fún àwọn ọmọ wọn, kí àwọn ọmọ wọn sì sọ fún àwọn ọmọ tiwọn náà. Ohun tí eṣú wẹẹrẹ jẹ kù, ọ̀wọ́ àwọn eṣú ńláńlá jẹ ẹ́. Èyí tí ọ̀wọ́ àwọn eṣú ńláńlá jẹ kù, àwọn eṣú wẹẹrẹ mìíràn jẹ ẹ́, èyí tí àwọn eṣú wẹẹrẹ yìí jẹ kù, àwọn eṣú tí ń jẹ nǹkan run jẹ ẹ́ tán. Ẹ jí lójú oorun, ẹ̀yin ọ̀mùtí, ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń mu waini, nítorí waini tuntun tí a já gbà kúrò lẹ́nu yín. Orílẹ̀-èdè kan ti dojú kọ ilẹ̀ mi, wọ́n lágbára, wọ́n pọ̀, wọn kò sì lóǹkà; eyín wọn dàbí ti kinniun. Ọ̀gàn wọn sì dàbí ti abo kinniun. Wọ́n ti run ọgbà àjàrà mi, wọ́n ti já àwọn ẹ̀ka igi ọ̀pọ̀tọ́ mi, wọ́n ti bó gbogbo èèpo ara rẹ̀, wọ́n ti wó o lulẹ̀, àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì ti di funfun. Ẹ sọkún bí ọmọge tí ó fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora, nítorí ikú àfẹ́sọ́nà ìgbà èwe rẹ̀. A ti dáwọ́ ẹbọ ohun jíjẹ ati ti ohun mímu dúró ní ilé OLUWA, àwọn alufaa tíí ṣe iranṣẹ OLUWA ń ṣọ̀fọ̀. Ilẹ̀ ti gbẹ, ó ń ṣọ̀fọ̀, nítorí a ti run ọkà, àjàrà ti tán, epo olifi sì ń tán lọ. Ẹ banújẹ́, ẹ̀yin àgbẹ̀, ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn ẹ̀yin tí ẹ̀ ń tọ́jú ọgbà àjàrà, nítorí ọkà alikama ati ọkà baali, ati nítorí pé ohun ọ̀gbìn ti ṣègbé. Èso àjàrà ti rọ, igi ọ̀pọ̀tọ́ sì ti ń gbẹ. Igi pomegiranate, igi ọ̀pẹ ati igi ápù, ati gbogbo àwọn igi eléso ti gbẹ, inú ọmọ eniyan kò sì dùn mọ́. Ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí ẹ sì sọkún, ẹ̀yin alufaa, ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin tí ẹ̀ ǹ ṣiṣẹ́ ní ibi pẹpẹ ìrúbọ. Ẹ̀yin òjíṣẹ́ Ọlọrun mi, ẹ wọlé, kí ẹ sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora sùn, nítorí a ti dáwọ́ ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu dúró ní ilé Ọlọrun yín. Ẹ kéde ààwẹ̀, kí ẹ sì pe àpèjọ. Ẹ pe àwọn àgbààgbà, ati gbogbo àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà jọ sí ilé OLUWA Ọlọrun yín, kí ẹ sì kígbe pe OLUWA. Ó ṣe! Ọjọ́ náà ń bọ̀, ọjọ́ OLUWA dé tán! Ọjọ́ náà yóo dé bí ọjọ́ ìparun láti ọ̀dọ̀ Olodumare. A ti gba oúnjẹ lẹ́nu yín, níṣojú yín, bẹ́ẹ̀ ni a gba ayọ̀ ati inú dídùn kúrò ní ilé Ọlọrun wa. Irúgbìn díbàjẹ́ sinu ebè, àwọn ilé ìṣúra ti di ahoro, àwọn àká ti wó lulẹ̀, nítorí kò sí ọkà láti kó sinu wọn mọ́. Àwọn ẹran ọ̀sìn ń kérora, àwọn agbo mààlúù dààmú, nítorí pé kò sí pápá oko fún wọn; àwọn agbo aguntan pàápàá dààmú. Ìwọ ni mo kígbe pè, OLUWA, nítorí iná ti jó gbogbo pápá oko run, ó sì ti jó gbogbo igi oko run. Àwọn ẹranko ìgbẹ́ pàápàá ń kígbe sí ọ, Ọlọrun, nítorí gbogbo àwọn odò ti gbẹ tán, àwọn pápá oko sì ti jóná. Ẹ fun fèrè ní Sioni, ẹ kéde ìdágìrì lórí òkè mímọ́ mi. Kí gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà wárìrì, nítorí ọjọ́ OLUWA ń bọ̀, ó sì ti dé tán. Yóo jẹ́ ọjọ́ òkùnkùn ati ìbànújẹ́, ọjọ́ ìkùukùu ati òkùnkùn biribiri. Àwọn ọmọ ogun yóo bo gbogbo òkè ńlá, bí ìgbà tí òkùnkùn bá ń ṣú bọ̀. Irú rẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí ní ìgbà àtijọ́, bẹ́ẹ̀ ni irú rẹ̀ kò sì tún ní ṣẹlẹ̀ mọ́ títí lae. Iná ń jó àjórun níwájú wọn, ahọ́n iná ń yọ lálá lẹ́yìn wọn. Ilẹ̀ náà dàbí ọgbà Edẹni níwájú wọn, ṣugbọn lẹ́yìn wọn, ó dàbí aṣálẹ̀ tí ó ti di ahoro, kò sì sí ohun tí yóo bọ́ lọ́wọ́ wọn. Ìrísí wọn dàbí ìrísí ẹṣin, wọ́n sì ń sáré bí ẹṣin tí ń lọ ojú ogun. Ìró wọn dàbí ìró kẹ̀kẹ́ ogun, wọ́n ń bẹ́ lórí àwọn òkè ńlá. Ìró wọn dàbí ìró iná tí ń jó pápá, bí ìgbà tí àwọn alágbára ọmọ ogun múra fún ogun. Ìdààmú bá àwọn orílẹ̀-èdè tí ó bá ti fojú kàn wọ́n, gbogbo ọkàn á rẹ̀wẹ̀sì. Wọ́n ń sáré bí akọni, wọ́n ń fo ògiri bí ọmọ ogun. Wọ́n tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́, ẹnikẹ́ni kò sì yà kúrò ní ọ̀nà tirẹ̀. Wọn kò fi ara gbún ara wọn, olukuluku ń lọ ní ọ̀nà tirẹ̀; wọ́n kọlu àwọn nǹkan ààbò láìní ìdádúró. Wọ́n ń gun odi ìlú, wọ́n ń sáré lórí odi. Wọ́n ń gun orí ilé wọlé, wọ́n gba ojú fèrèsé bẹ́ sinu ọ̀dẹ̀dẹ̀ bí olè. Ilẹ̀ ń mì tìtì níwájú wọn, ọ̀run sì ń wárìrì, oòrùn, òṣùpá ati àwọn ìràwọ̀ ṣókùnkùn. OLUWA sọ̀rọ̀ níwájú àwọn ọmọ ogun rẹ̀, nítorí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pọ̀ lọpọlọpọ, alágbára ni ẹni tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ. Ọjọ́ ńlá ati ọjọ́ ẹ̀rù ni ọjọ́ OLUWA! Ta ló lè faradà á? OLUWA ní, “Ẹ yipada sí mi tọkàntọkàn nisinsinyii, pẹlu ààwẹ̀, ẹkún ati ìkẹ́dùn, Ìrònúpìwàdà tòótọ́ ni mò ń fẹ́, kì í ṣe pé kí ẹ fa aṣọ yín ya nìkan.” Ẹ yipada sí OLUWA Ọlọrun yín, nítorí olóore-ọ̀fẹ́ ati aláàánú ni. Kì í yára bínú, Ó kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, a sì máa dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan. Ó ṣeéṣe kí Ọlọrun ṣàánú, kí ó yí ibinu rẹ̀ pada, kí ó sì tú ibukun rẹ̀ sílẹ̀, kí ẹ lè rú ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu fún OLUWA Ọlọrun yín. Ẹ fọn fèrè ní òkè Sioni, ẹ kéde ààwẹ̀ kí ẹ sì pe àpéjọ. Ẹ pe gbogbo eniyan jọ, kí ẹ sì ya ìjọ eniyan sí mímọ́. Ẹ pe àwọn àgbààgbà jọ, ẹ kó àwọn ọmọde ati àwọn ọmọ ọwọ́ jọ. Kí ọkọ iyawo jáde láti inú yàrá rẹ̀, kí iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé náà jáde ninu yàrá rẹ̀. Kí àwọn alufaa, àwọn iranṣẹ Ọlọrun, sọkún láàrin ẹnu ọ̀nà àbáwọlé ati pẹpẹ ìrúbọ. Kí wọ́n wí pé “OLUWA, dá àwọn eniyan rẹ sí, má sì sọ ilẹ̀ rẹ di ohun ẹ̀gàn ati ohun ẹ̀sín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù. Má jẹ́ kí àwọn eniyan láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù bèèrè pé, ‘Níbo ni Ọlọrun wọn wà?’ ” Nígbà náà ni ara bẹ̀rẹ̀ sí ta OLUWA nítorí ilẹ̀ rẹ̀, ó sì ṣàánú fún àwọn eniyan rẹ̀. OLUWA dá àwọn eniyan rẹ̀ lóhùn pé, “Wò ó! N óo fun yín ní ọkà, waini ati òróró, ẹ óo ní ànítẹ́rùn. N kò ní sọ yín di ẹni ẹ̀gàn láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù mọ́. N óo kó àwọn eṣú láti ìhà àríwá jìnnà kúrò lọ́dọ̀ yín, n óo lé wọn lọ sinu aṣálẹ̀ níbi tí kò sí nǹkankan. N óo lé àwọn tí wọ́n wà níwájú lọ sí inú òkun, ní apá ìlà oòrùn, n óo sì lé àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn lọ sí inú òkun, ní apá ìwọ̀ oòrùn. Òkú wọn yóo máa rùn; n óo pa wọ́n run nítorí ibi ńlá tí wọ́n ṣe. Má bẹ̀rù, ìwọ ilẹ̀, jẹ́ kí inú rẹ máa dùn, kí o sì máa yọ̀, nítorí OLUWA ti ṣe nǹkan ńlá. Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ẹranko inú igbó, nítorí ewéko gbogbo ni ó tutù, igi gbogbo ti so èso, igi ọ̀pọ̀tọ́ ati ọgbà àjàrà sì ti so jìnwìnnì. “Ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ará Sioni, kí inú yín máa dùn ninu OLUWA Ọlọrun yín; nítorí ó ti da yín láre, ó ti fun yín ní àkọ́rọ̀ òjò, ó ti rọ ọpọlọpọ òjò fun yín: ati òjò àkọ́rọ̀, ati àrọ̀kẹ́yìn òjò, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀. Gbogbo ibi ìpakà ni yóo kún fún ọkà, ìkòkò waini ati ti òróró yín yóo kún àkúnwọ́sílẹ̀. Gbogbo ohun tí ẹ pàdánù ní àwọn ọdún tí àwọn ọmọ ogun mi tí mo rán si yín ti jẹ oko yín; ati èyí tí eṣú wẹẹrẹ jẹ, ati èyí tí eṣú ńláńlá jẹ, gbogbo rẹ̀ ni n óo dá pada fun yín. Ẹ óo jẹ oúnjẹ àjẹyó ati àjẹtẹ́rùn, ẹ óo sì yin orúkọ OLUWA Ọlọrun yín, tí ó ṣe ohun ìyanu ńlá fun yín, ojú kò sì ní ti àwọn eniyan mi mọ́ lae. Ẹ óo mọ̀ pé mo wà láàrin Israẹli; ati pé èmi OLUWA ni Ọlọrun yín, kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi mọ́. Ojú kò sì ní ti àwọn eniyan mi mọ́ lae. “Lẹ́yìn náà, nígbà tí ó bá yá, n óo tú ẹ̀mí mi jáde sára gbogbo eniyan, àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin yín yóo máa sọ àsọtẹ́lẹ̀, àwọn àgbààgbà yín yóo máa lá àlá, àwọn ọdọmọkunrin yín yóo sì máa ríran. Bákan náà, nígbà tí àkókò bá tó, n óo tú ẹ̀mí mi jáde sára àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin yín. “Ìtàjẹ̀sílẹ̀ yóo pọ̀, n óo sì fi iná, ati òpó èéfín sí ojú ọ̀run, ati sórí ilẹ̀ ayé; yóo jẹ́ ìkìlọ̀ fun yín. Oòrùn yóo ṣókùnkùn, òṣùpá yóo pọ́n rẹ̀bẹ̀tẹ̀ bí ẹ̀jẹ̀, kí ọjọ́ OLUWA tí ó lẹ́rù tó dé. Ṣugbọn gbogbo àwọn tí wọ́n bá ké pe orúkọ OLUWA ni a óo gbàlà. Àwọn kan yóo sá àsálà ní òkè Sioni, ní Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ, àwọn tí OLUWA pè yóo sì wà lára àwọn tí wọn yóo sá àsálà. “Wò ó! Nígbà tó bá yá, tí mo bá dá ire Juda ati ti Jerusalẹmu pada, n óo kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí àfonífojì Jehoṣafati, n óo sì dá wọn lẹ́jọ́ níbẹ̀; nítorí ohun tí wọ́n ti ṣe sí Israẹli, àwọn eniyan mi. Wọ́n ti fọ́n wọn káàkiri sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, wọ́n sì ti pín ilẹ̀ mi. Wọ́n ti ṣẹ́ gègé lórí àwọn eniyan mi, wọ́n ti ta àwọn ọmọkunrin wọn, wọ́n fi owó wọn san owó aṣẹ́wó, wọ́n sì ta àwọn ọmọbinrin wọn, wọ́n fi owó wọn ra ọtí waini. “Kí ni mo fi ṣe yín rí, ẹ̀yin ilẹ̀ Tire, ati ilẹ̀ Sidoni ati gbogbo agbègbè Filistini? Ṣé ẹ̀ ń gbẹ̀san nǹkankan lára mi ni? Bí ó bá jẹ́ pé ẹ̀ ń gbẹ̀san nǹkankan ni, n óo da ẹ̀san tí ẹ̀ ń gbà le yín lórí kíákíá; nítorí ẹ ti kó fadaka ati wúrà ati àwọn ìṣúra mi olówó iyebíye lọ sí ilé oriṣa yín. Ẹ ta àwọn ará Juda ati àwọn ará Jerusalẹmu fún àwọn ará Giriki, ẹ kó wọn jìnnà réré sí ilẹ̀ wọn. Ṣugbọn nisinsinyii, n óo gbé wọn dìde níbi tí ẹ tà wọ́n sí, n óo sì gbẹ̀san ìwà yín lára ẹ̀yin alára. N óo ta àwọn ọmọ yín ọkunrin ati àwọn ọmọ yín obinrin lẹ́rú fún àwọn ará Juda. Wọn yóo sì tà wọ́n fún àwọn ará Sabea, orílẹ̀-èdè tí ó jìnnà réré; nítorí OLUWA ni ó sọ bẹ́ẹ̀.” Ẹ kéde èyí láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè. Ẹ múra ogun, ẹ rú àwọn akọni sókè. Kí gbogbo àwọn ọmọ ogun súnmọ́ tòsí, ogun yá! Ẹ fi irin ọkọ́ yín rọ idà, ẹ fi dòjé yín rọ ọ̀kọ̀, kí àwọn tí wọn kò lágbára wí pé, “Ọmọ ogun ni mí.” Ẹ yára, ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè tí ẹ wà ní àyíká, ẹ parapọ̀ níbẹ̀. Rán àwọn ọmọ ogun rẹ wá, OLUWA. Jẹ́ kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè dìde, kí wọ́n wá sí àfonífojì Jehoṣafati, nítorí níbẹ̀ ni n óo ti ṣe ìdájọ́ gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó wà ní àyíká. Ẹ ti dòjé bọ oko, nítorí àkókò ìkórè ti tó, ẹ lọ fún ọtí waini nítorí ibi ìfúntí ti kún. Ìkòkò ọtí ti kún àkúnwọ́sílẹ̀, nítorí ìkà wọ́n pọ̀. Ogunlọ́gọ̀ wà ní àfonífojì ìdájọ́, nítorí ọjọ́ OLUWA kù sí dẹ̀dẹ̀ níbẹ̀. Oòrùn ati òṣùpá ti ṣókùnkùn, àwọn ìràwọ̀ kò sì tan ìmọ́lẹ̀ mọ́. OLUWA kígbe láti Sioni, ó sọ̀rọ̀ láti Jerusalẹmu; ọ̀run ati ayé mì tìtì, ṣugbọn OLUWA ni ààbò fún àwọn eniyan rẹ̀, òun ni ibi ààbò fún Israẹli. “Israẹli, o óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA, Ọlọrun rẹ, èmi ni mò ń gbé Sioni, òkè mímọ́ mi. Jerusalẹmu yóo di ìlú mímọ́, àwọn àjèjì kò sì ní ṣẹgun mọ́. “Nígbà náà, àwọn òkè ńlá yóo kún fún èso àjàrà, agbo mààlúù yóo sì pọ̀ lórí àwọn òkè kéékèèké. Gbogbo àwọn odò Juda yóo kún fún omi. Odò kan yóo bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn láti ilé OLUWA, yóo sì bomi rin àfonífojì Ṣitimu. “Ijipti yóo di aṣálẹ̀; Edomu yóo sì di ẹgàn, nítorí ìwà ipá tí wọ́n hù sí àwọn ará Juda, nítorí wọ́n ti pa àwọn aláìṣẹ̀ ní ilẹ̀ wọn. Ṣugbọn àwọn eniyan yóo máa gbé ilẹ̀ Juda títí lae, wọn óo sì máa gbé ìlú Jerusalẹmu láti ìrandíran. N óo gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn tí ẹ pa, n kò sì ní dá ẹlẹ́bi sí, nítorí èmi OLUWA ni mò ń gbé Sioni.” Ìran tí Amosi, ọ̀kan ninu àwọn darandaran Tekoa, rí nípa Israẹli nìyí, nígbà ayé Usaya, ọba Juda, ati Jeroboamu, ọmọ Jehoaṣi, ọba Israẹli, ní ọdún meji ṣáájú ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ tí ilẹ̀ fi mì jìgìjìgì. Amosi ní: “OLUWA bú ramúramù lórí Òkè Sioni, ó fọhùn ní Jerusalẹmu; àwọn pápá tútù rọ, ewéko tútù orí òkè Kamẹli sì rẹ̀.” OLUWA ní, “Àwọn ará Damasku ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà. Wọ́n mú ohun èlò ìpakà onírin ṣómúṣómú, wọ́n fi pa àwọn ará Gileadi ní ìpa ìkà. Nítorí náà, n óo sọ iná sí ààfin Hasaeli, yóo sì jó ibi ààbò Benhadadi kanlẹ̀. N óo fọ́ ìlẹ̀kùn odi ìlú Damasku. N óo sì pa gbogbo àwọn ará àfonífojì Afeni run. Wọn óo mú ọba Betedeni lọ sí ìgbèkùn; òun ati àwọn ará Siria yóo lọ sí ìgbèkùn ní ilẹ̀ Kiri.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. Ó ní: “Àwọn ará Gasa ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí odidi orílẹ̀-èdè kan ni wọ́n kó lẹ́rú, tí wọ́n lọ tà fún àwọn ará Edomu. N óo sọ iná sí ìlú Gasa, yóo sì jó ibi ààbò rẹ̀ ní àjórun. N óo pa gbogbo àwọn ará Aṣidodu run ati ọba Aṣikeloni; n óo jẹ ìlú Ekironi níyà, àwọn ará Filistia yòókù yóo sì ṣègbé.” OLUWA Ọlọrun ló sọ bẹ́ẹ̀. Ó ní: “Àwọn ará Tire ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí wọ́n kó odidi orílẹ̀-èdè kan lẹ́rú lọ tà fún àwọn ará Edomu. Wọn kò sì ranti majẹmu tí wọ́n bá àwọn arakunrin wọn dá. Nítorí náà n óo sọ iná sí orí odi ìlú Tire, yóo sì jó ibi ààbò rẹ̀ ní àjórun.” OLUWA ní: “Àwọn ará Edomu ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí wọ́n dojú idà kọ arakunrin wọn, láìṣàánú wọn, wọ́n bínú kọjá ààlà, títí lae sì ni ìrúnú wọn. Nítorí náà, n óo rán iná sí ìlú Temani, yóo sì jó ibi ààbò Bosira ní àjórun.” OLUWA ní: “Àwọn ará Amoni ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; wọ́n fi ìwà wọ̀bìà bẹ́ inú àwọn aboyún ilẹ̀ Gileadi, láti gba ilẹ̀ kún ilẹ̀ wọn. Nítorí náà, n óo sọ iná sí orí odi ìlú Raba, yóo sì jó ibi ààbò rẹ̀ ní àjórun. Ariwo yóo sọ ní ọjọ́ ogun, omi òkun yóo ru sókè ní ọjọ́ ìjì; ọba wọn ati àwọn ìjòyè rẹ̀ yóo sì lọ sí ìgbèkùn.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. OLUWA ní: “Àwọn ará Moabu ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí wọ́n sọná sí egungun ọba Edomu, wọ́n sun ún, ó jóná ráúráú. Nítorí náà, n óo sọ iná sí Moabu, yóo sì jó àwọn ibi ààbò Kerioti ní àjórun. Ninu ariwo ogun ati ti fèrè ni Moabu yóo parun sí, n óo sì pa ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀ run.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. Ó ní: “Àwọn ará Juda ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí wọ́n ti kọ òfin èmi OLUWA sílẹ̀, wọn kò sì rìn ní ìlànà mi. Àwọn oriṣa irọ́ tí àwọn baba wọn ń bọ, ti ṣì wọ́n lọ́nà. Nítorí náà, n óo sọ iná sí Juda, yóo sì jó àwọn ibi ààbò Jerusalẹmu ní àjórun.” OLUWA ní: “Àwọn ará Israẹli ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí pé wọ́n ta olódodo nítorí fadaka, wọ́n sì ta aláìní nítorí bàtà ẹsẹ̀ meji. Wọ́n rẹ́ àwọn talaka jẹ, wọ́n sì yí ẹjọ́ àwọn tí ìyà ń jẹ po. Baba ati ọmọ ń bá ẹrubinrin kanṣoṣo lòpọ̀, wọ́n sì ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́. Wọ́n sùn káàkiri yí pẹpẹ inú ilé Ọlọrun wọn ká, lórí aṣọ tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn onígbèsè wọn; wọ́n ń mu ọtí tí àwọn kan fi san owó ìtanràn. “Bẹ́ẹ̀ sì ni èmi ni mo pa àwọn ará Amori run fún wọn, àwọn géńdé, tí wọ́n ga bí igi kedari, tí wọ́n sì lágbára bí igi oaku; mo run wọ́n tèsotèso, tigbòǹgbò-tigbòǹgbò. Èmi fúnra mi ni mo mu yín jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti, mo mu yín la aṣálẹ̀ fún ogoji ọdún, kí ẹ lè gba ilẹ̀ àwọn ará Amori. Mo yan àwọn kan ninu àwọn ọmọ yín ní wolii mi, mo sì yan àwọn mìíràn ninu wọn ní Nasiri. Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli? Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Ṣugbọn ẹ̀ ń mú kí àwọn Nasiri mu ọtí, ẹ sì ń dá àwọn wolii mi lẹ́kun, pé wọn kò gbọdọ̀ sọ àsọtẹ́lẹ̀ mọ́. Wò ó, n óo tẹ̀ yín ní àtẹ̀rẹ́ ní ibùgbé yín, bí ìgbà tí ọkọ̀ kọjá lórí eniyan. Ní ọjọ́ náà, àárẹ̀ yóo mú àwọn tí wọ́n lè sáré; ipá àwọn alágbára yóo pin, akikanju kò sì ní lè gba ara rẹ̀ sílẹ̀. Tafàtafà kò ní lè dúró, ẹni tí ó lè sáré kò ní lè sá àsálà; bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣin kò ní lè gba ara wọn kalẹ̀. Ìhòòhò ni àwọn akọni láàrin àwọn ọmọ ogun yóo sálọ ní ọjọ́ náà.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA sọ nípa yín, gbogbo ẹ̀yin tí a kó jáde láti ilẹ̀ Ijipti: OLUWA ní, “Ẹ̀yin nìkan ni mo mọ̀ láàrin gbogbo aráyé, nítorí náà, n óo jẹ yín níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín. “Ṣé eniyan meji lè jọ máa lọ sí ibìkan láìjẹ́ pé wọ́n ní àdéhùn? “Ṣé kinniun a máa bú ninu igbó láìjẹ́ pé ó ti pa ẹran? “Àbí ọmọ kinniun a máa bú ninu ihò rẹ̀ láìṣe pé ọwọ́ rẹ̀ ti ba nǹkan? “Ṣé tàkúté a máa mú ẹyẹ nílẹ̀, láìṣe pé eniyan ló dẹ ẹ́ sibẹ? “Àbí tàkúté a máa ta lásán láìṣe pé ó mú nǹkan? “Ṣé eniyan lè fọn fèrè ogun láàrin ìlú kí àyà ará ìlú má já? “Àbí nǹkan ibi lè ṣẹlẹ̀ ní ìlú láìṣe pé OLUWA ni ó ṣe é? “Dájúdájú OLUWA Ọlọrun kì í ṣe ohunkohun láì kọ́kọ́ fi han àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀. “Kinniun bú ramúramù, ta ni ẹ̀rù kò ní bà? “OLUWA Ọlọrun ti sọ̀rọ̀, ta ló gbọdọ̀ má sọ àsọtẹ́lẹ̀?” Kéde fún àwọn ibi ààbò Asiria, ati àwọn ibi ààbò ilẹ̀ Ijipti, sọ pé: “Ẹ kó ara yín jọ sí orí àwọn òkè Samaria, kí ẹ sì wo rúdurùdu ati ìninilára tí ń ṣẹlẹ̀ ninu rẹ̀. “Àwọn eniyan wọnyi ń kó nǹkan tí wọ́n fi ipá ati ìdigunjalè gbà sí ibi ààbò wọn, wọn kò mọ̀ bí à á tíí ṣe rere.” Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní: “Ọ̀tá yóo yí ilẹ̀ náà po, wọn yóo wó ibi ààbò yín, wọn yóo sì kó ìṣúra tí ó wà ní àwọn ilé ìṣúra rẹ̀.” OLUWA ní: “Bí olùṣọ́-aguntan tií rí àjẹkù ẹsẹ̀ meji péré, tabi etí kan gbà kalẹ̀ lẹ́nu kinniun, ninu odidi àgbò, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún àwọn ọmọ Israẹli, tí ń gbé Samaria: díẹ̀ ninu wọn ni yóo là, àwọn tí wọn ń sùn lórí ibùsùn olówó iyebíye.” OLUWA Ọlọrun, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní: “Ẹ gbọ́, kí ẹ sì kìlọ̀ fún ìdílé Jakọbu. Ní ọjọ́ tí n óo bá jẹ Israẹli níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, n óo jẹ pẹpẹ Bẹtẹli níyà, n óo kán àwọn ìwo tí ó wà lára pẹpẹ, wọn yóo sì bọ́ sílẹ̀. N óo wó ilé tí ẹ kọ́ fún ìgbà òtútù ati èyí tí ẹ kọ́ fún ìgbà ooru; bẹ́ẹ̀ ni àwọn ilé tí ẹ fi eyín erin kọ́ ati àwọn ilé ńláńlá yín yóo parẹ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin obinrin Samaria, ẹ̀yin tí ẹ sanra bíi mààlúù Baṣani, tí ẹ wà lórí òkè Samaria, tí ẹ̀ ń ni àwọn aláìní lára, tí ẹ̀ ń tẹ àwọn talaka ní àtẹ̀rẹ́, tí ẹ̀ ń wí fún àwọn ọkọ yín pé, “Ẹ gbé ọtí wá kí á mu.” OLUWA Ọlọrun ti fi ìwà mímọ́ rẹ̀ búra pé, “Ọjọ́ ń bọ̀, tí wọn óo fi ìwọ̀ fà yín lọ, gbogbo yín pátá ni wọn óo fi ìwọ̀ ẹja fà lọ, láì ku ẹnìkan. Níbi tí odi ti ya ni wọn óo ti fà yín jáde, tí ẹ óo tò lẹ́sẹẹsẹ; a óo sì ko yín lọ sí Harimoni.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. OLUWA ní, “Ẹ wá sí Bẹtẹli, kí ẹ wá máa dẹ́ṣẹ̀ níbẹ̀, kí ẹ sì wá fi ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ ní Giligali; ẹ máa mú ẹbọ yín wá ní àràárọ̀, ati ìdámẹ́wàá yín ní ọjọ́ kẹta kẹta. Ẹ fi burẹdi tí ó ní ìwúkàrà rú ẹbọ ọpẹ́, ẹ kéde ẹbọ àtinúwá, kí ẹ sì fọ́nnu nípa rẹ̀; nítorí bẹ́ẹ̀ ni ẹ fẹ́ máa ṣe, ẹ̀yin ọmọ Israẹli. “Mo jẹ́ kí ìyàn mú ní gbogbo ìlú yín, kò sì sí oúnjẹ ní gbogbo ilẹ̀ yín; sibẹsibẹ ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi. N kò jẹ́ kí òjò rọ̀ mọ́, nígbà tí ìkórè ku oṣù mẹta; mò ń rọ òjò ní ìlú kan, kò sì dé ìlú keji; ó rọ̀ ní oko kan, ó dá ekeji sí, àwọn nǹkan ọ̀gbìn oko tí òjò kò rọ̀ sí sì rọ. Nítorí náà, ìlú meji tabi mẹta ń wá omi lọ sí ẹyọ ìlú kan wọn kò sì rí tó nǹkan; sibẹsibẹ ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “Mo jẹ́ kí nǹkan oko yín ati èso àjàrà yín rẹ̀ dànù, mo mú kí wọn rà; eṣú jẹ igi ọ̀pọ̀tọ́ ati igi olifi yín, sibẹsibẹ ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi. “Mo fi irú àwọn àjàkálẹ̀ àrùn tí ó jà ní Ijipti ba yín jà, mo fi idà pa àwọn ọdọmọkunrin yín lójú ogun; mo kó ẹṣin yín lọ, mo mú kí òórùn àwọn tí wọ́n kú ninu àgọ́ yín wọ̀ yín nímú; sibẹsibẹ ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi. Mo pa àwọn kan ninu yín run bí mo ti pa Sodomu ati Gomora run, ẹ dàbí àjókù igi tí a yọ ninu iná; sibẹsibẹ, ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi. Nítorí náà, n óo jẹ yín níyà, ẹ̀yin ọmọ Israẹli; nítorí irú ìyà tí n óo fi jẹ yín, ẹ múra sílẹ̀ de ìdájọ́ Ọlọrun yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli!” Ẹ gbọ́! Ọlọrun ni ó dá òkè ńlá ati afẹ́fẹ́, tí ń fi èrò ọkàn rẹ̀ han eniyan, Ọlọrun ní ń sọ òwúrọ̀ di òru, tí sì ń rìn níbi gíga-gíga ayé; OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀! Ẹ fetí sí orin arò tí mò ń kọ le yín lórí, ẹ̀yin ìdílé Israẹli: Israẹli, ọdọmọbinrin, ṣubú, kò ní lè dìde mọ́ lae. Ó di ìkọ̀sílẹ̀ ní ilẹ̀ rẹ̀, kò sì sí ẹni tí yóo gbé e dìde. OLUWA Ọlọrun ní: “Ninu ẹgbẹrun ọmọ ogun tí ìlú Israẹli kan bá rán jáde, ọgọrun-un péré ni yóo kù. Ninu ọgọrun-un tí ìlú mìíràn bá rán jáde, mẹ́wàá péré ni yóo kù.” OLUWA ń sọ fún ilé Israẹli pé: “Ẹ wá mi, kí ẹ sì yè; ẹ má lọ sí Bẹtẹli, ẹ má sì wọ Giligali, tabi kí ẹ kọjá lọ sí Beeriṣeba; nítorí a óo kó Giligali lọ sí oko ẹrú, Bẹtẹli yóo sì di asán.” Ẹ wá OLUWA, kí ẹ sì yè; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, yóo rọ̀jò iná sórí ilé Josẹfu, ati sí ìlú Bẹtẹli; kò sì ní sí ẹni tí yóo lè pa á. Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ẹ̀bi fún aláre, tí ẹ sì tẹ òdodo mọ́lẹ̀. Ẹni tí ó dá àwọn ìràwọ̀ Pileiadesi ati Orioni, tí ó sọ òkùnkùn biribiri di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀, òun níí sọ ọ̀sán di òru; òun ni ó dá omi òkun sórí ilẹ̀, OLUWA ni orúkọ rẹ̀. Òun ni ó ń mú ìparun wá sórí àwọn alágbára, kí ìparun lè bá ibi ààbò wọn. Wọ́n kórìíra ẹni tí ń bá ni wí lẹ́nu ibodè, wọ́n sì kórìíra ẹni tí ń sọ òtítọ́. Ẹ̀ ń rẹ́ talaka jẹ, ẹ sì ń fi ipá gba ọkà wọn. Nítòótọ́, ẹ ti fi òkúta tí wọ́n dárà sí kọ́ ilé, ṣugbọn ẹ kò ní gbé inú wọn; ẹ ti ṣe ọgbà àjàrà dáradára, ṣugbọn ẹ kò ní mu ninu ọtí waini ibẹ̀. Gbogbo ìwà àìdára yín ni mo mọ̀, mo sì mọ̀ bí ẹ̀ṣẹ̀ yín ti tóbi tó, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fìyà jẹ olódodo, tí ẹ̀ ń gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀, tí ẹ sì ń du àwọn aláìní ní ẹ̀tọ́ wọn lẹ́nu ibodè. Nítorí náà, ẹni tí ó bá gbọ́n yóo dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní irú àkókò yìí, nítorí pé àkókò burúkú ni. Ire ni kí ẹ máa wá, kì í ṣe ibi kí ẹ lè wà láàyè; nígbà náà ni OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun yóo wà pẹlu yín, bí ẹ ti jẹ́wọ́ rẹ̀. Ẹ kórìíra ibi, kí ẹ sì fẹ́ ire, ẹ jẹ́ kí ìdájọ́ òdodo gbilẹ̀ lẹ́nu ibodè yín; bóyá OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun yóo ṣàánú fún àwọn ọmọ ilé Josẹfu yòókù. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, àní OLUWA ní: “Ẹkún yóo wà ní gbogbo ìta gbangba, wọn yóo sì máa kọ ‘Háà! Háà!’ nígboro. Wọn yóo pe àwọn àgbẹ̀ pàápàá, ati àwọn tí wọn ń fi ẹkún sísun ṣe iṣẹ́ ṣe, láti wá sọkún àwọn tí wọ́n kú. Wọn yóo sọkún ninu gbogbo ọgbà àjàrà yín, nítorí pé n óo gba ààrin yín kọjá. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń retí ọjọ́ OLUWA, ẹ gbé! Kí ni ẹ fẹ́ fi ọjọ́ OLUWA ṣe? Ọjọ́ òkùnkùn ni, kì í ṣe ọjọ́ ìmọ́lẹ̀. Yóo dàbí ìgbà tí eniyan ń sálọ fún kinniun, tí ó pàdé ẹranko beari lọ́nà; tabi tí ó sá wọ ilé rẹ̀, tí ó fọwọ́ ti ògiri, tí ejò tún bù ú jẹ. Ṣebí òkùnkùn ni ọjọ́ OLUWA, kì í ṣe ìmọ́lẹ̀! Ọjọ́ ìṣúdudu láìsí ìmọ́lẹ̀ ni. Ọlọrun ní, “Mo kórìíra ọjọ́ àsè yín, n kò sì ní inú dídùn sí àwọn àpéjọ yín. Bí ẹ tilẹ̀ rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ yín sí mi, n kò ní gbà wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní fojú rere wo ẹran àbọ́pa tí ẹ mú wá bí ọrẹ ẹbọ alaafia. Ẹ dákẹ́ ariwo orin yín; n kò fẹ́ gbọ́ ohùn orin hapu yín mọ́. Ṣugbọn ẹ jẹ́ kí òtítọ́ máa ṣàn bí omi, kí òdodo sì máa ṣàn bí odò tí kò lè gbẹ. “Ẹ gbọ́, ilé Israẹli, ǹjẹ́ ẹ mú ẹbọ ati ọrẹ wá fún mi ní gbogbo ogoji ọdún tí ẹ fi wà ninu aṣálẹ̀? Ṣugbọn nisinsinyii, ẹ̀ ń sin ère Sakuti, ọba yín, ati Kaiwani, oriṣa ìràwọ̀ yín, ati àwọn ère tí ẹ ṣe fún ara yín. Nítorí náà, n óo ko yín lọ sí ìgbèkùn níwájú Damasku.” OLUWA, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọlọrun àwọn Ọmọ Ogun, ni ó sọ bẹ́ẹ̀. Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n wà ninu ìdẹ̀ra ní Sioni, ati àwọn tí wọn ń gbé orí òkè Samaria láìléwu, àwọn eniyan ńláńlá ní Israẹli, tí ó jẹ́ àkọ́kọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn tí àwọn eniyan gbójúlé. Ẹ lọ wo ìlú Kane; ẹ ti ibẹ̀ lọ sí Hamati, ìlú ńlá nì, lẹ́yìn náà ẹ lọ sí ìlú Gati, ní ilẹ̀ àwọn ará Filistia. Ṣé wọ́n sàn ju àwọn orílẹ̀-èdè yín lọ ni? Tabi agbègbè wọn tóbi ju tiyín lọ? Ẹ kò fẹ́ gbà pé ọjọ́ ibi ti súnmọ́ tòsí; ṣugbọn ẹ̀ ń ṣe nǹkan tí yóo mú kí ọjọ́ ẹ̀rù tètè dé. Àwọn tí ń sùn sórí ibùsùn tí wọ́n fi eyín erin ṣe gbé! Àwọn tí wọ́n nà kalẹ̀ lórí ìrọ̀gbọ̀kú wọn, tí wọn ń jẹ ẹran ọ̀dọ́ aguntan, ati ti ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù láti inú agbo ẹran wọn! Àwọn tí ń fi hapu kọ orin ìrégbè, tí wọ́n sì ń ṣe ohun èlò orin fún ara wọn bíi Dafidi. Àwọn tí wọn ń fi abọ́ mu ọtí, tí wọn ń fi òróró olówó iyebíye para, ṣugbọn tí wọn kò bìkítà fún ìparun Josẹfu. Nítorí náà, àwọn ni wọn yóo kọ́kọ́ lọ sí ìgbèkùn, gbogbo àsè ati ayẹyẹ àwọn tí wọn ń nà kalẹ̀ sórí ibùsùn yóo dópin. OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ti fi ara rẹ̀ búra, ó ní: “Mo kórìíra ìwà ìgbéraga Jakọbu, ati gbogbo àwọn ibi ààbò rẹ̀; n óo mú ọwọ́ kúrò lọ́rọ̀ ìlú náà ati gbogbo nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀.” Bí ó bá ku eniyan mẹ́wàá ninu ìdílé kan, gbogbo wọn yóo kú. Nígbà tí ẹni tí ó jẹ́ olùdarí ìsìnkú bá kó eegun òkú jáde, tí ó bá bi àwọn eniyan tí ó kù ninu ilé pé, “Ǹjẹ́ ó ku ẹnikẹ́ni mọ́?” Wọn yóo dá a lóhùn pé, “Rárá.” Nígbà náà ni olùdarí ìsìnkú yóo sọ pé, “Ẹ dákẹ́, ẹ ṣọ́ra, a kò gbọdọ̀ tilẹ̀ dárúkọ OLUWA.” Wò ó! OLUWA pàṣẹ pé, a óo wó àwọn ilé ńlá, ati àwọn ilé kéékèèké lulẹ̀ patapata. Ṣé ẹṣin a máa sáré lórí àpáta? Àbí eniyan a máa fi àjàgà mààlúù pa ilẹ̀ lórí òkun? Ṣugbọn ẹ ti sọ ẹ̀tọ́ di májèlé, ẹ sì ti sọ èso òdodo di ohun kíkorò. Ẹ fọ́nnu pé ẹ̀yin ni ẹ ṣẹgun ìlú Lodebari, ẹ̀ ń wí pé: “Ṣebí agbára wa ni a fi gba ìlú Kanaimu.” OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní: “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, n óo rán orílẹ̀-èdè kan láti pọn yín lójú, wọn yóo sì fìyà jẹ yín láti ibodè Hamati, títí dé odò Araba.” OLUWA Ọlọrun fi ìran kan hàn mí! Ó ń kó ọ̀wọ́ eṣú jọ ní àkókò tí koríko ìkẹyìn bẹ̀rẹ̀ sí yọ sókè, lẹ́yìn tí wọ́n ti gé koríko ti ọba tán. Nígbà tí àwọn eṣú náà ti jẹ gbogbo koríko ilẹ̀ náà tán, mo ní, “OLUWA Ọlọrun, jọ̀wọ́ dáríjì àwọn eniyan rẹ. Báwo ni àwọn ọmọ Jakọbu yóo ṣe là, nítorí pé wọ́n kéré níye?” OLUWA bá yí ìpinnu rẹ̀ pada, ó ní, “Ohun tí o rí kò ní ṣẹlẹ̀.” OLUWA Ọlọrun tún fi ìran mìíràn hàn mí: mo rí i tí Ọlọrun pe iná láti fi jẹ àwọn eniyan rẹ̀ níyà. Iná náà jó ibú omi, ráúráú ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jó ilẹ̀ pàápàá. Nígbà náà ni mo dáhùn pé: “OLUWA Ọlọrun, jọ̀wọ́, dáwọ́ dúró. Báwo ni àwọn ọmọ Jakọbu yóo ṣe là, nítorí wọ́n kéré níye?” OLUWA bá yí ìpinnu rẹ̀ pada, ó ní, “Ohun tí o rí kò ní ṣẹlẹ̀.” OLUWA Ọlọrun tún fi ìran mìíràn hàn mí: mo rí i tí OLUWA mú okùn ìwọ̀n àwọn mọlémọlé lọ́wọ́; ó dúró lẹ́bàá ògiri tí a ti fi okùn ìwọ̀n àwọn mọlémọlé wọ̀n. Ó bi mí pé: “Amosi, kí ni o rí?” Mo bá dáhùn pé, “Okùn ìwọ̀n àwọn mọlémọlé.” Ó ní: “Wò ó! Mo ti fi okùn ìwọ̀n àwọn mọlémọlé sí ààrin àwọn ọmọ Israẹli, eniyan mi; n kò ní fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́. Gbogbo ibi gíga Isaaki yóo di ahoro, ilé mímọ́ Israẹli yóo parun, n óo yọ idà sí ìdílé ọba Jeroboamu.” Nígbà náà ni Amasaya, alufaa Bẹtẹli, ranṣẹ sí Jeroboamu, ọba Israẹli pé: “Amosi ń dìtẹ̀ mọ́ ọ láàrin àwọn ọmọ Israẹli, ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóo sì ba gbogbo ilẹ̀ yìí jẹ́. Ó ń wí pé, ‘Jeroboamu yóo kú sójú ogun, gbogbo ilé Israẹli ni a óo sì kó lẹ́rú lọ.’ ” Amasaya sọ fún Amosi pé, “Ó tó gẹ́ẹ́, ìwọ aríran, pada lọ sí ilẹ̀ Juda, máa lọ sọ àsọtẹ́lẹ̀ níbẹ̀, kí wọ́n sì máa fún ọ ní oúnjẹ. Má sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní Bẹtẹli mọ́, nítorí ibi mímọ́ ni, fún ọba ati fún gbogbo orílẹ̀-èdè.” Amosi bá dáhùn, ó ní: “Èmi kì í ṣe wolii tabi ọmọ wolii, darandaran ni mí, èmi a sì tún máa tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́. OLUWA ló pè mí níbi iṣẹ́ mi, òun ló ní kí n lọ máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún Israẹli, eniyan òun. Gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA nisinsinyii, ṣé o ní kí n má sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli mọ́, kí n má sì waasu fún àwọn ọmọ Isaaki mọ́? Nítorí náà, gbọ́ ohun tí OLUWA sọ: ‘Iyawo rẹ yóo di aṣẹ́wó láàrin ìlú, àwọn ọmọ rẹ lọkunrin ati lobinrin yóo kú sójú ogun, a óo pín ilẹ̀ rẹ fún àwọn ẹlòmíràn; ìwọ pàápàá yóo sì kú sí ilẹ̀ àwọn alaigbagbọ; láìṣe àní àní, a óo kó àwọn ọmọ Israẹli lọ sí ìgbèkùn.’ ” OLUWA Ọlọrun, tún fi ìran mìíràn hàn mí. Lójú ìran, mo rí agbọ̀n èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn kan. OLUWA bèèrè pé, “Amosi, kí ni ò ń wò yìí?” Mo sì dáhùn pé, “Agbọ̀n èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ni.” OLUWA bá sọ pé: “Òpin ti dé sí Israẹli, àwọn eniyan mi, n kò sì ní fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́. Nígbà tó bá yá, orin inú tẹmpili yóo di ẹkún, òkú yóo sùn lọ kítikìti níbi gbogbo, a óo kó wọn dà síta ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń rẹ́ àwọn aláìní jẹ, tí ẹ múra láti pa àwọn talaka run lórí ilẹ̀ patapata. Ẹ̀ ń sọ pé: “Nígbà wo ni ìsinmi oṣù titun yóo parí, kí á lè rí ààyè ta ọkà wa? Nígbà wo sì ni ọjọ́ ìsinmi yóo kọjá, kí á lè rí ààyè ta alikama, kí á lè gbówó lé ọjà wa, kí á sì lo òṣùnwọ̀n èké, láti rẹ́ àwọn oníbàárà wa jẹ; kí á lè fi fadaka ra talaka, kí á lè ta aláìní, kí á sì fi owó rẹ̀ ra bàtà, kí á sì ta alikama tí kò dára?” OLUWA ti fi ògo Jakọbu búra; ó ní, “Dájúdájú n kò ní gbàgbé ẹyọ kan ninu iṣẹ́ ọwọ́ yín. Ǹjẹ́ kò yẹ kí ilẹ̀ náà mì tìtì nítorí ọ̀rọ̀ yìí kí àwọn eniyan tí ń gbé orí rẹ̀ sì máa ṣọ̀fọ̀? Gbogbo rẹ̀ yóo ru sókè bí odò Naili, yóo máa lọ sókè sódò, yóo sì fà bí odò Naili ti Ijipti. Ní ọjọ́ náà, n óo mú kí oòrùn wọ̀ ní ọjọ́kanrí, ilẹ̀ yóo sì ṣókùnkùn ní ọ̀sán gangan. N óo yí àsè àjọ̀dún yín pada sí ọ̀fọ̀, n óo sọ orin yín di ẹkún; n óo sán aṣọ ìbànújẹ́ mọ́ gbogbo yín nídìí, n óo sì mú kí orí gbogbo yín pá; ẹ óo dàbí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ kanṣoṣo, ọjọ́ náà yóo korò ju ewúro lọ.” OLUWA Ọlọrun ní, “Ọjọ́ ń bọ̀ tí n óo rán ìyàn sí ilẹ̀ náà; kì í ṣe ìyàn, oúnjẹ, tabi ti omi, ìran láti ọ̀dọ̀ OLUWA ni kò ní sí. Wọn yóo máa lọ káàkiri láti òkun dé òkun, láti ìhà àríwá sí ìhà ìlà oòrùn. Wọn yóo máa sá sókè sódò láti wá ọ̀rọ̀ Ọlọrun, ṣugbọn wọn kò ní rí i. Nígbà tó bá yá, àwọn ọdọmọkunrin ati àwọn wundia yóo dákú nítorí òùngbẹ. Gbogbo àwọn tí wọn ń fi oriṣa Aṣima ti Samaria búra, tí wọn ń wí pé: ‘Bí oriṣa rẹ ti wà láàyè, ìwọ Dani,’ ati, ‘Bí ọ̀nà Beeriṣeba ti wà láàyè;’ gbogbo wọn yóo ṣubú, wọn kò sì ní dìde mọ́.” Mo rí OLUWA, ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ, ó pàṣẹ pé, “Lu àwọn òpó tẹmpili títí tí gbogbo àtẹ́rígbà rẹ̀ yóo fi mì tìtì, tí yóo sì wó lé gbogbo àwọn eniyan lórí. N óo jẹ́ kí ogun pa àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù lára wọn, Kò ní sí ẹyọ ẹnìkan ninu wọn tí yóo lè sálọ, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí ẹnìkan tí yóo sá àsálà. Bí wọ́n tilẹ̀ gbẹ́ ilẹ̀ tí ó jìn bí isà òkú, ọwọ́ mi yóo tẹ̀ wọ́n níbẹ̀; bí wọ́n gòkè lọ sí ojú ọ̀run, n óo wọ́ wọn lulẹ̀ láti ibẹ̀. Bí wọ́n bá sápamọ́ sórí òkè Kamẹli, n óo wá wọn kàn níbẹ̀; n óo sì mú wọn. Bí wọ́n bá sá kúrò níwájú mi, tí wọ́n sápamọ́ sí ìsàlẹ̀ òkun, n óo pàṣẹ fún ejò níbẹ̀, yóo sì bù wọ́n jẹ. Bí àwọn ọ̀tá bá kó wọn lẹ́rú, tí wọn ń kó wọn lọ, n óo pàṣẹ pé kí àwọn ọ̀tá pa wọ́n. N óo dójúlé wọn láti ṣe wọ́n ní ibi, n kò ní ṣe wọ́n ní rere.” OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, òun ló fọwọ́ kan ilẹ̀, tí ilẹ̀ sì yọ́, tí gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀, tí gbogbo nǹkan ru sókè bí odò Naili, tí ó sì lọ sílẹ̀ bí odò Naili ti Ijipti; OLUWA tí ó kọ́ ilé gíga rẹ̀ sí ojú ọ̀run, tí ó gbé awọsanma lé orí ilẹ̀ ayé tí ó pe omi òkun jáde, tí ó sì dà á sórí ilẹ̀, OLUWA ni orúkọ rẹ̀. Ọlọrun ní, “Ṣebí bí ẹ ti jẹ́ sí mi ni àwọn ará Etiopia náà jẹ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli? Àbí kì í ṣe bí mo ti mú àwọn ará Filistia jáde láti ìlú Kafitori, tí mo mú àwọn Siria jáde láti ìlú Kiri, ni mo mú ẹ̀yin náà jáde láti Ijipti. Wò ó! Èmi OLUWA Ọlọrun ti fojú sí orílẹ̀-èdè tí ń dẹ́ṣẹ̀ lára, n óo sì pa á run lórí ilẹ̀ ayé; ṣugbọn, n kò ní run gbogbo ìran Jakọbu. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “N óo pàṣẹ pé kí wọ́n gbo gbogbo Israẹli jìgìjìgì láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè, bí ìgbà tí wọ́n bá fi ajọ̀ ku èlùbọ́, ṣugbọn kóró kan kò ní bọ́ sílẹ̀. Gbogbo àwọn tí wọn ń dẹ́ṣẹ̀ láàrin àwọn eniyan mi ni ogun yóo pa, gbogbo àwọn tí wọ́n ń sọ pé, ‘Ibi kankan kò ní bá wa!’ “Ní ọjọ́ náà, n óo gbé àgọ́ Dafidi tí ó ti wó ró. N óo tún odi rẹ̀ mọ, n óo tún un kọ́ yóo sì rí bí ó ti wà tẹ́lẹ̀ rí. Àwọn ọmọ Israẹli yóo ṣẹgun àwọn tí wọ́n kù ní Edomu, ati gbogbo orílẹ̀-èdè tí à ń fi orúkọ mi pè. Èmi OLUWA, tí n óo ṣe bí mo ti wí, èmi ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “Ọjọ́ ń bọ̀, tí ọkà yóo so jìnwìnnì, tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní lè kórè rẹ̀ tán kí àkókò gbígbin ọkà mìíràn tó dé. Ọgbà àjàrà yóo so, tóbẹ́ẹ̀ tí a kò ní lè fi ṣe waini tán kí àkókò ati gbin òmíràn tó dé. Ọtí waini dídùn yóo máa kán sílẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá, ọtí waini yóo sì máa ṣàn jáde lára àwọn òkè kéékèèké. N óo dá ire Israẹli, àwọn eniyan mi, pada, wọn yóo tún àwọn ìlú tí wọ́n ti wó kọ́, wọn yóo sì máa gbé inú wọn. Wọn yóo gbin àjàrà, wọn yóo sì mu ọtí waini rẹ̀. Wọn yóo ṣe ọgbà, wọn yóo sì jẹ èso rẹ̀. N óo fẹsẹ̀ àwọn eniyan mi múlẹ̀ lórí ilẹ̀ tí mo fún wọn, a kò sì ní ṣí wọn nípò pada mọ́ lórí ilẹ̀ tí mo fún wọn. Èmi OLUWA Ọlọrun yín ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” Ìran tí Ọbadaya rí nìyí, OLUWA Ọlọrun sọ nípa Edomu pé: A ti gbọ́ ìròyìn láti ọ̀dọ̀ OLUWA, ó sì ti rán iranṣẹ rẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè pé: “Ẹ múra, ẹ jẹ́ kí á lọ bá Edomu jagun!” Ó sọ fún Edomu pé, “Wò ó, n óo sọ ọ́ di yẹpẹrẹ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù; gbogbo ayé pátá ni yóo máa fi ọ́ ṣẹ̀sín. Ìgbéraga rẹ ti tàn ọ́ jẹ, ìwọ tí ò ń gbé inú pàlàpálá òkúta, tí ibùgbé rẹ wà lórí òkè gíga, tí o sì ń wí ninu ọkàn rẹ pé, ‘Ta ni ó lè fà mí lulẹ̀?’ Bí o tilẹ̀ fò lọ sókè bí ẹyẹ idì, tí ó tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí ààrin àwọn ìràwọ̀, láti òkè náà ni n óo ti fà ọ́ lulẹ̀. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “Bí àwọn olè bá wá bá ọ lóru, tí àwọn ọlọ́ṣà bá wá ká ọ mọ́lé lọ́gànjọ́, ṣé wọn kò ní hàn ọ́ léèmọ̀? Ṣebí ohun tí wọ́n bá fẹ́ ninu ẹrù rẹ ni wọn óo kó? Bí àwọn tí wọn ń kórè àjàrà bá wá sọ́dọ̀ rẹ, ṣebí wọn a máa fi díẹ̀ sílẹ̀? Ogun ti kó Esau, gbogbo ìṣúra rẹ̀ ni wọ́n ti kó tán! Gbogbo àwọn tí wọ́n bá ọ dá majẹmu ti tàn ọ́ jẹ, wọ́n sì ti lé ọ títí dé ààlà ilẹ̀ rẹ; àwọn tí ẹ jọ ń gbé ní alaafia tẹ́lẹ̀ ti di ọ̀tá rẹ; àwọn ọ̀rẹ́ tí o gbẹ́kẹ̀lé ti dẹ tàkúté sílẹ̀ dè ọ́, o kò sì mọ̀. “Ní ọjọ́ náà, ni n óo pa àwọn ọlọ́gbọ́n run ní Edomu, òye wọn yóo sì di òfo ní òkè Esau. Ìwọ ìlú Temani, ìbẹ̀rùbojo yóo dé bá àwọn akọni rẹ, gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ní òkè Esau ni a óo sì fi idà pa. “Nítorí ìwà ìkà tí ẹ hù sí àwọn ọmọ Israẹli, arakunrin yín, ojú yóo tì yín a óo sì pa yín run títí lae. Ní ọjọ́ tí àwọn ọ̀tá ń kó ọrọ̀ wọn lọ, tí àwọn àjèjì wọ inú ìlú wọn, tí àwọn ọ̀tá sì ń ṣẹ́ gègé lórí Jerusalẹmu, ẹ dúró, ẹ̀ ń wò wọ́n; ẹ sì dàbí ọ̀kan ninu wọn. O kì bá tí fi arakunrin rẹ ṣẹ̀sín ní ọjọ́ ìpọ́njú rẹ̀; o kì bá tí jẹ́ kí inú rẹ dùn, ní ọjọ́ ìparun àwọn eniyan Juda; o kì bá tí fọ́nnu ní ọjọ́ ìbànújẹ́ wọn. O kì bá tí wọ ìlú àwọn eniyan mi ní ọjọ́ ìpọ́njú wọn; o kì bá tí fi wọ́n ṣẹ̀sín ní ọjọ́ àjálù wọn; o kì bá tí kó wọn lẹ́rù ní ọjọ́ ìpọ́njú wọn. O kì bá tí dúró sí oríta, kí o máa mú àwọn tí wọn ń gbìyànjú láti sá àsálà; o kì bá tí fà wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́ ní ọjọ́ ìpọ́njú wọn. “Ọjọ́ ìdájọ́ OLUWA fẹ́rẹ̀ dé sórí àwọn orílẹ̀-èdè; a óo san án fún ọ, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Ohun tí o bá ṣe, yóo pada sí orí ara rẹ. Ẹ̀yin eniyan mi, bí ẹ ti jìyà ní òkè mímọ́ mi, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè náà yóo jìyà; wọn óo jìyà yóo tẹ́ wọn lọ́rùn, wọn yóo sì wà gẹ́gẹ́ bí ẹni pé wọn kò sí rí. “Ṣugbọn ní òkè Sioni ni àwọn tí wọ́n bá sá àsálà yóo máa gbé, yóo sì jẹ́ òkè mímọ́; àwọn ọmọ Jakọbu yóo gba ohun ìní wọn pada. Ilé Jakọbu yóo dàbí iná, ilé Josẹfu yóo dàbí ọ̀wọ́ iná, ilé Esau yóo sì dàbí àgékù koríko. Wọn yóo jó ilé Esau; àwọn ìran Esau yóo jó àjórun láìku ẹnìkan; nítorí pé OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. Àwọn tí wọn ń gbé Nẹgẹbu yóo gba òkè Edomu, àwọn tí wọ́n wà ní ẹsẹ̀ Ṣefela yóo gba ilẹ̀ àwọn ará Filistia; wọn yóo gba gbogbo agbègbè Efuraimu ati ilẹ̀ Samaria, àwọn ará Bẹnjamini yóo sì gba ilẹ̀ Gileadi. Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ní oko ẹrú ní ilẹ̀ Hala wọ́n óo gba ilẹ̀ Fonike títí dé Sarefati; àwọn eniyan Jerusalẹmu tí wọ́n wà ní oko ẹrú ní ilẹ̀ Sefaradi yóo gba àwọn ìlú tí ó wà ní Nẹgẹbu. Àwọn olùgbàlà yóo lọ láti Sioni, wọn yóo jọba lórí òkè Edomu; ìjọba náà yóo sì jẹ́ ti OLUWA.” OLUWA bá Jona ọmọ Amitai sọ̀rọ̀, ó ní, “Dìde, lọ sí Ninefe, ìlú ńlá nì, kéde, kí o sì kìlọ̀ fún wọn pé mo rí gbogbo ìwà burúkú wọn!” Ṣugbọn Jona gbéra ó fẹ́ sálọ sí Taṣiṣi, kí ó lè kúrò níwájú OLUWA. Ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Jọpa, ó sì rí ọkọ̀ ojú omi kan tí ń lọ sí Taṣiṣi níbẹ̀. Ó san owó ọkọ̀, ó bá bọ́ sinu ọkọ̀, ó fẹ́ máa bá a lọ sí Taṣiṣi kí ó sì sá kúrò níwájú OLUWA. Ṣugbọn OLUWA gbé ìjì kan dìde lójú omi òkun, afẹ́fẹ́ náà le tóbẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ ojú omi fẹ́rẹ̀ ya. Ẹ̀rù ba àwọn tí wọn ń tu ọkọ̀, olukuluku bá bẹ̀rẹ̀ sí ké pe oriṣa rẹ̀, wọ́n ń da ẹrù wọn tí ó wà ninu ọkọ̀ sinu òkun kí ọkọ̀ lè fúyẹ́. Ṣugbọn Jona ti lọ dùbúlẹ̀ sí ìsàlẹ̀ ọkọ̀, ó sì ti sùn lọ fọnfọn. Olórí àwọn tí wọn ń tu ọkọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó wí fún un pé, “Kí ló ṣe ọ́ tí ò ń sùn, olóorun? Dìde, ké pe ọlọrun rẹ, bóyá a jẹ́ ṣàánú wa, kí á má baà ṣègbé.” Wọ́n bá dámọ̀ràn láàrin ara wọn, wọ́n ní “Ẹ jẹ́ kí á ṣẹ́ gègé, kí á lè mọ ẹni tí ó fà á, tí nǹkan burúkú yìí fi dé bá wa.” Wọ́n ṣẹ́ gègé, gègé bá mú Jona. Wọ́n bi í pé, “Sọ fún wa, nítorí ta ni nǹkan burúkú yìí fi dé bá wa? Kí ni iṣẹ́ rẹ? Níbo ni o ti wá? Níbo ni orílẹ̀-èdè rẹ? Inú ẹ̀yà wo ni o sì ti wá?” Ó bá dá wọn lóhùn pé: “Heberu ni mí, ẹ̀rù OLUWA ni ó bà mí, àní Ọlọrun ọ̀run, tí ó dá òkun ati ilẹ̀ gbígbẹ.” Ẹ̀rù ba àwọn tí wọn ń tu ọkọ̀ náà gidigidi, wọ́n sọ fún un pé, “Kí ni o dánwò yìí?” Nítorí wọ́n mọ̀ pé Jona ń sá kúrò níwájú OLUWA ni, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún wọn. Wọ́n bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ni kí á ṣe sí ọ, kí ìjì omi òkun lè dáwọ́ dúró? Nítorí ìjì náà sá túbọ̀ ń le sí i ni.” Ó bá sọ fún wọn pé, “Ẹ gbé mi jù sinu òkun, ìjì náà yóo sì dáwọ́ dúró, nítorí mo mọ̀ pé nítorí mi ni òkun fi ń ru.” Sibẹsibẹ, àwọn tí wọn ń tu ọkọ̀ náà gbìyànjú láti tu ọkọ̀ wọn pada sórí ilẹ̀, ṣugbọn kò ṣeéṣe, nítorí pé, afẹ́fẹ́ líle dojú kọ wọ́n, ìjì náà sì ń pọ̀ sí i. Wọ́n bá gbadura sí OLUWA, wọ́n ní, “A bẹ̀ ọ́, OLUWA, má jẹ́ kí á ṣègbé nítorí ti ọkunrin yìí, má sì ka ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ yìí sí wa lọ́rùn; nítorí bí o ti fẹ́ ni ò ń ṣe.” Wọ́n bá gbé Jona jù sinu òkun, òkun sì dákẹ́rọ́rọ́. Ẹ̀rù OLUWA ba àwọn tí wọ́n wà ninu ọkọ̀ lọpọlọpọ, wọ́n rúbọ, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLUWA. OLUWA bá pèsè ẹja ńlá kan tí ó gbé Jona mì. Jona sì wà ninu ẹja náà fún ọjọ́ mẹta. Jona gbadura sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀ láti inú ẹja náà, ó ní, “Ninu ìpọ́njú mi, mo ké pe OLUWA, ó sì dá mi lóhùn, mo ké pè é láti inú isà òkú, ó sì gbóhùn mi. Nítorí pé, ó gbé mi jù sinu ibú, ní ààrin agbami òkun, omi òkun sì bò mí mọ́lẹ̀; ọwọ́ agbára rírú omi òkun rẹ̀ sì ń wọ́ kọjá lórí mi. Nígbà náà ni mo sọ pé, ‘A ti ta mí nù kúrò níwájú rẹ; báwo ni n óo ṣe tún rí tẹmpili mímọ́ rẹ?’ Omi bò mí mọ́lẹ̀, ibú omi yí mi ká, koríko inú omi sì wé mọ́ mi lórí. Mo já sí ibi tí ó jìn jùlọ ninu òkun, àní ibi tí ẹnikẹ́ni kò lọ ní àlọ-bọ̀ rí. Ṣugbọn ìwọ, OLUWA Ọlọrun mi, o mú ẹ̀mí mi jáde láti inú ibú náà. Nígbà tí ẹ̀mí mi ń bọ́ lọ, mo gbadura sí ìwọ OLUWA, o sì gbọ́ adura mi ninu tẹmpili mímọ́ rẹ. Àwọn tí wọn ń sin àwọn oriṣa lásánlàsàn kọ̀, wọn kò pa ìlérí wọn sí ọ mọ́. Ṣugbọn n óo rúbọ sí ọ pẹlu ohùn ọpẹ́, n óo sì san ẹ̀jẹ́ mi. Ti OLUWA ni ìgbàlà!” OLUWA bá pàṣẹ fún ẹja tí ó gbé Jona mì, ó sì lọ pọ̀ ọ́ sí èbúté, lórí ilẹ̀ gbígbẹ. OLUWA tún bá Jona sọ̀rọ̀ nígbà keji, ó ní: “Dìde, lọ sí Ninefe, ìlú ńlá nì, kí o sì kéde iṣẹ́ tí mo rán ọ fún gbogbo eniyan ibẹ̀.” Jona bá dìde, ó lọ sí Ninefe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA. Ninefe jẹ́ ìlú tí ó tóbi, ó gbà tó ìrìn ọjọ́ mẹta láti la ìlú náà já. Jona rin ìlú náà fún odidi ọjọ́ kan, ó sì ń kéde pé: “Níwọ̀n ogoji ọjọ́ sí i, Ninefe óo parun.” Àwọn ará Ninefe gba ọ̀rọ̀ Ọlọrun gbọ́, wọ́n bá kéde pé kí gbogbo eniyan gbààwẹ̀, àtọmọdé, àtàgbà, wọ́n sì da aṣọ ọ̀fọ̀ bora. Nígbà tí ọ̀rọ̀ náà dé etígbọ̀ọ́ ọba Ninefe ó dìde lórí ìtẹ́ rẹ̀, ó bọ́ ẹ̀wù oyè sílẹ̀, ó wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ó sì jókòó ninu eérú. Ó bá ní kí wọn kéde fún àwọn ará Ninefe, pé, “Ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀ pàṣẹ pé, eniyan tabi ẹranko, tabi ẹran ọ̀sìn kankan kò gbọdọ̀ fi ẹnu kan ohunkohun. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ, wọn kò sì gbọdọ̀ mu. Ṣugbọn kí gbogbo wọn fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora, kí wọ́n sì fi gbogbo ọkàn wọn gbadura sí Ọlọrun. Kí olukuluku pa ọ̀nà burúkú ati ìwà ipá tí ó wà lọ́wọ́ rẹ̀ tì. A kì í mọ̀, bóyá Ọlọrun lè yí ọkàn rẹ̀ pada, kí ó má jẹ wá níyà mọ́. Bóyá yóo tilẹ̀ dá ibinu rẹ̀ dúró, kò sì ní pa wá run.” Nígbà tí Ọlọrun rí i pé wọ́n ti pa ìwà burúkú wọn tì, Ọlọrun náà bá yí ìpinnu rẹ̀ pada, kò sì jẹ wọ́n níyà mọ́. Ṣugbọn bí Ọlọrun ti ṣe yìí kò dùn mọ́ Jona ninu rárá, inú bí i. Ó bá gbadura sí OLUWA, ó ní: “OLUWA, ṣebí ohun tí mo sọ láti ìbẹ̀rẹ̀ nìyí, nígbà tí mo wà ní orílẹ̀-èdè mi? Nítorí náà ni mo ṣe sa gbogbo ipá mi láti sálọ sí Taṣiṣi; nítorí mo mọ̀ pé Ọlọrun onífẹ̀ẹ́ ati aláàánú ni ọ́, o ní sùúrù, o kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, ò sì máa yí ibi tí o bá ti pinnu láti ṣe pada. Ǹjẹ́ nisinsinyii, OLUWA, mo bẹ̀ ọ́, gba ẹ̀mí mi, nítorí pé, ó sàn fún mi láti kú ju pé kí n wà láàyè lọ.” OLUWA bá dá Jona lóhùn pé, “Ǹjẹ́ ó yẹ kí o bínú?” Jona bá jáde kúrò láàrin ìlú náà, ó sì lọ jókòó sí ìhà ìlà oòrùn ìlú náà. Ó pa àtíbàbà kan sibẹ, ó jókòó ní ìbòòji lábẹ́ rẹ̀, ó ń retí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ìlú náà. OLUWA bá rán ìtàkùn kan, ó fà á bo ibẹ̀, o sì ṣíji bo orí ibi tí Jona wà kí ó lè fún un ní ìtura ninu ìnira rẹ̀. Inú Jona dùn gidigidi nítorí ìtàkùn yìí. Ṣugbọn Ọlọrun rán kòkòrò kan ní àárọ̀ ọjọ́ keji, ó jẹ ìtàkùn náà, ó sì rọ. Nígbà tí oòrùn yọ, Ọlọrun mú kí afẹ́fẹ́ ìhà ìlà oòrùn fẹ́, oòrùn sì pa Jona tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi fẹ́rẹ̀ dákú. Ó sọ fún Ọlọrun pé kí ó gba ẹ̀mí òun. Ó ní, “Ó sàn kí n kú ju pé kí n wà láàyè lọ.” Ọlọrun bá bi Jona pé, “Ǹjẹ́ o lẹ́tọ̀ọ́ láti bínú nítorí ìtàkùn yìí?” Jona dáhùn, ó ní: “Ó tọ́ kí n bínú títí dé ojú ikú.” Nígbà náà ni OLUWA dá a lóhùn pé, “ìwọ ń káàánú ìtàkùn lásánlàsàn, tí o kò ṣiṣẹ́ fún, tí kì í sìí ṣe ìwọ ni o mú un dàgbà, àní ìtàkùn tí ó hù ní òru ọjọ́ kan, tí ó sì gbẹ ní ọjọ́ keji. Ṣé kò yẹ kí èmi foríji Ninefe, ìlú ńlá nì, tí àwọn ọmọde inú rẹ̀ ju ọ̀kẹ́ mẹfa (120,000) lọ, tí wọn kò mọ ọwọ́ ọ̀tún yàtọ̀ sí tòsì, pẹlu ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn tí ó wà ninu ìlú náà?” Ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ fún Mika, ará Moreṣeti nípa Jerusalẹmu ati Samaria nìyí, ní àkókò ìjọba Jotamu, ati ti Ahasi ati ti Hesekaya, àwọn ọba Juda. Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, fetí sílẹ̀, ìwọ ayé, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀. Kí OLUWA fúnrarẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́rìí tí yóo takò yín, àní OLUWA, láti inú tẹmpili rẹ̀ mímọ́. Wò ó, OLUWA ń jáde bọ̀ láti inú ilé rẹ̀, yóo sọ̀kalẹ̀, yóo sì rìn lórí àwọn òkè gíga ayé. Àwọn òkè ńlá yóo yọ́ lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, bí ìda tíí yọ̀ níwájú iná; àwọn àfonífojì yóo pínyà gẹ́gẹ́ bí omi tí a dà sílẹ̀ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu, ati ti ilé Israẹli ni gbogbo nǹkan wọnyi yóo ṣe ṣẹlẹ̀. Kí ló fa ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu? Ṣebí ìlú Samaria ni. Kí sì ni ẹ̀ṣẹ̀ ilé Juda? Ṣebí ìlú Jerusalẹmu ni. OLUWA ní, “Nítorí náà, n óo sọ Samaria di àlàpà ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú, yóo di ọgbà ìgbin àjàrà sí; gbogbo òkúta tí a fi kọ́ ọ ni n óo fọ́nká, sinu àfonífojì, ìpìlẹ̀ rẹ̀ yóo sì hàn síta. Gbogbo ère oriṣa rẹ̀ ni a óo fọ́ túútúú, a óo sì jó gbogbo owó iṣẹ́ àgbèrè rẹ̀ níná. Gbogbo ère rẹ̀ ni n óo kójọ bí òkítì, a óo sì kọ̀ wọ́n tì; nítorí pé owó àgbèrè ni ó fi kó wọn jọ, ọrọ̀ rẹ̀ yóo pada sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ń bá a ṣe àgbèrè. “Nítorí èyí, n óo sọkún, n óo sì pohùnréré ẹkún; n óo rìn káàkiri ní ìhòòhò láìwọ bàtà. N óo máa ké kiri bí ọ̀fàfà, n óo sì ṣọ̀fọ̀ bí ẹyẹ ògòǹgò. Nítorí pé egbò Samaria kò lè ṣe é wò jinná; egbò náà sì ti ran Juda, ó ti dé ẹnubodè àwọn eniyan mi, àní, Jerusalẹmu.” Ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ ìṣubú wa ní ìlú Gati, ẹ má sọkún rárá; ẹ̀yin ará ìlú Beti Leafira, ẹ máa gbé ara yílẹ̀. Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Ṣafiri ẹ máa rìn ní ìhòòhò pẹlu ìtìjú lọ sí ìgbèkùn. Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Saanani, ẹ má jáde kúrò níbẹ̀, nítorí ẹkún àwọn ará Beteseli, yóo fihàn yín pé kò sí ààbò yín lọ́dọ̀ wọn. Àwọn ará Marotu ń retí ire pẹlu gbogbo ọkàn wọn, nítorí pé ibi ti dé sí bodè Jerusalẹmu láti ọ̀dọ̀ OLUWA. Ẹ̀yin ará Lakiṣi, ẹ de kẹ̀kẹ́ ogun yín mọ́ ẹṣin; ọ̀dọ̀ yín ni ẹ̀ṣẹ̀ ti kọ́ bẹ̀rẹ̀, tí ó sì tàn lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Jerusalẹmu, nítorí pé nípasẹ̀ yín ni Israẹli ṣe dẹ́ṣẹ̀. Nítorí náà, ẹ óo fún àwọn ará Moreṣeti Gati ní ẹ̀bùn ìdágbére; ilé Akisibu yóo sì jẹ́ ohun ìtànjẹ fún àwọn ọba Israẹli. Ẹ̀yin ará Mareṣa, n óo tún jẹ́ kí àwọn ọ̀tá borí yín; ògo Israẹli yóo sì lọ sí ọ̀dọ̀ Adulamu. Ẹ̀yin ará Juda, ẹ fá irun orí yín láti ṣọ̀fọ̀ nítorí àwọn ọmọ yín tí ẹ fẹ́ràn; kí orí yín pá bí orí igún, nítorí a óo kó àwọn ọmọ yín ní ìgbèkùn kúrò lọ́dọ̀ yín. Ègbé ni fún àwọn tí wọn ń gbìmọ̀ ìkà, tí wọ́n sì ń gbèrò ibi lórí ibùsùn wọn. Nígbà tí ilẹ̀ bá sì mọ́, wọn á ṣe ibi tí wọn ń gbèrò. Nítorí pé ó wà ní ìkáwọ́ wọn láti ṣe é. Bí ilẹ̀ kan bá wọ̀ wọ́n lójú, wọn á gbà á lọ́wọ́ onílẹ̀; bí ilé kan ló bá sì wù wọ́n, wọn á fi ipá gbà á lọ́wọ́ onílé; wọ́n ń fìyà jẹ eniyan ati ilé rẹ̀, àní eniyan ati ohun ìní rẹ̀. Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí; ó ní, “Wò ó, mò ń gbèrò ibi kan sí ìdílé yìí; tí ẹ kò ní lè bọ́rí ninu rẹ̀; ẹ kò ní rìn pẹlu ìgbéraga, nítorí pé àkókò burúkú ni yóo jẹ́. Ní ọjọ́ náà, wọn yóo máa fi yín kọrin ẹlẹ́yà, wọn yóo sì sọkún le yín lórí tẹ̀dùntẹ̀dùn. Wọn yóo wí pé, ‘A ti parun patapata; ó ti pa ìpín àwọn eniyan mi dà; ẹ wò bí ó ti yí i kúrò lọ́dọ̀ mi, ó pín ilẹ̀ wa fún àwọn tí wọ́n ṣẹgun wa.’ ” Nítorí náà kò ní sí ìpín fún ẹnikẹ́ni ninu yín mọ́ nígbà tí a bá dá ilẹ̀ náà pada fún àwọn eniyan Ọlọrun. Àwọn eniyan náà ń pàrọwà fún mi pé, “Má waasu fún wa. Kò yẹ kí eniyan máa waasu nípa irú nǹkan báwọ̀nyí, Ọlọrun kò ní dójútì wá. Ṣé irú ọ̀rọ̀ tí eniyan máa sọ nìyí, ẹ̀yin ará ilé Jakọbu? Ṣé OLUWA kò ní mú sùúrù mọ́ ni? Àbí ẹ rò pé òun ni ó ń ṣe àwọn nǹkan wọnyi? Àbí ọ̀rọ̀ mi kì í ṣe àwọn tí wọ́n bá ń rin ọ̀nà ẹ̀tọ́ ní rere?” OLUWA ní: “Ṣugbọn ẹ dìde sí àwọn eniyan mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá, ẹ gba ẹ̀wù lọ́rùn àwọn tí wọn ń lọ lalaafia, àwọn tí wọn ń rékọjá lọ láìronú ogun. Ẹ lé àwọn aya àwọn eniyan mi jáde kúrò ninu ilé tí wọ́n fẹ́ràn; ẹ sì gba ògo mi kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn títí lae. Ẹ dìde, ẹ máa lọ, nítorí pé ìhín yìí kì í ṣe ibi ìsinmi; nítorí pé ẹ ti hùwà ìríra tí ń mú ìparun ńlá báni. “Wolii tí yóo máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ ati ẹ̀tàn ni àwọn eniyan wọnyi ń fẹ́, tí yóo sì máa waasu pé, ‘Ẹ óo ní ọpọlọpọ waini ati ọtí líle.’ “Dájúdájú, n óo kó gbogbo yín jọ, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, n óo kó àwọn ọmọ Israẹli yòókù jọ: n óo kó wọn pọ̀ bí aguntan, sinu agbo, àní bí agbo ẹran ninu pápá, ariwo yóo sì pọ̀ ninu agbo náà, nítorí ọ̀pọ̀ eniyan.” Ọlọrun tíí ṣí ọ̀nà ni yóo ṣáájú wọn; wọn yóo já irin ẹnubodè, wọn yóo sì gba ibẹ̀ jáde. Ọba wọn ni yóo ṣáájú wọn, OLUWA ni yóo sì ṣiwaju gbogbo wọn. Ẹ gbọ́, ẹ̀yin olórí ilé Jakọbu, ati ẹ̀yin alákòóso ilé Israẹli! Ṣé kò yẹ kí ẹ mọ̀ nípa ìdájọ́ òtítọ́? Ẹ̀yin tí ẹ kórìíra ohun rere, tí ẹ sì fẹ́ràn ibi, ẹ̀yin tí ẹ bó awọ lára àwọn eniyan mi, tí ẹ sì ya ẹran ara egungun wọn; ẹ̀yin ni ẹ jẹ ẹran ara àwọn eniyan mi, ẹ bó awọ kúrò lára wọn, ẹ sì fọ́ egungun wọn sí wẹ́wẹ́, ẹ gé wọn lékìrí lékìrí bí ẹran inú ìsaasùn, àní, bí ẹran inú ìkòkò. Nígbà tí ó bá yá, wọn yóo ké pe OLUWA, ṣugbọn kò ní dá wọn lóhùn; yóo fi ojú pamọ́ fún wọn, nítorí nǹkan burúkú tí wọ́n ṣe. Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA sọ nípa àwọn wolii tí wọn ń ṣi àwọn eniyan mi lọ́nà, tí wọn ń kéde “Alaafia” níbi tí wọ́n bá ti ń rí oúnjẹ jẹ, ṣugbọn tí wọn ń kéde ogun níbi tí kò bá ti sí oúnjẹ. Nítorí náà, alẹ́ yín yóo lẹ́ ṣugbọn àwọn aríran yín kò ní rí nǹkankan, òkùnkùn yóo kùn, àwọn woṣẹ́woṣẹ́ yín kò ní rí iṣẹ́ wò. Ògo àwọn wolii yóo wọmi, òkùnkùn yóo sì bò wọ́n. A óo dójúti àwọn aríran, ojú yóo sì ti àwọn woṣẹ́woṣẹ́; gbogbo wọn yóo fi ọwọ́ bo ẹnu wọn, nítorí pé, Ọlọrun kò ní dá wọn lóhùn. Ṣugbọn ní tèmi, mo kún fún agbára, ati ẹ̀mí OLUWA, ati fún ìdájọ́ òdodo ati ipá, láti kéde ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu, ati láti sọ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli fún wọn. Ẹ gbọ́, ẹ̀yin olórí ilé Jakọbu, ati ẹ̀yin alákòóso ilé Israẹli, ẹ̀yin tí ẹ kórìíra ìdájọ́ òdodo, tí ẹ sì ń gbé ẹ̀bi fún aláre. Ẹ̀yin tí ẹ fi owó ẹ̀jẹ̀ kọ́ Sioni, tí ẹ sì fi èrè ìwà burúkú kọ́ Jerusalẹmu. Àwọn aláṣẹ ń gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó ṣe ìdájọ́, àwọn alufaa ń gba owó iṣẹ́ wọn kí wọ́n tó kọ́ni, àwọn wolii ń gba owó kí wọ́n tó ríran; sibẹsibẹ, wọ́n gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, wọ́n ń wí pé, “Ṣebí OLUWA wà pẹlu wa? Nǹkan burúkú kò ní ṣẹlẹ̀ sí wa.” Nítorí náà, nítorí yín, a óo ro Sioni bí oko, Jerusalẹmu yóo di àlàpà, ahoro tẹmpili yóo sì di igbó kìjikìji. Nígbà tí ó bá yá, a óo fìdí òkè ilé OLUWA múlẹ̀ bí òkè tí ó ga jùlọ, a óo gbé e ga ju àwọn òkè yòókù lọ, àwọn eniyan yóo sì máa wọ́ wá sibẹ. Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè yóo wá, wọn yóo sì wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á lọ sórí òkè OLUWA, ẹ jẹ́ kí á lọ sí ilé Ọlọrun Jakọbu, kí ó lè kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, kí á sì lè máa tọ̀ ọ́.” Nítorí pé láti Sioni ni òfin yóo ti máa jáde, ọ̀rọ̀ OLUWA yóo sì máa jáde láti Jerusalẹmu. Yóo ṣe ìdájọ́ láàrin ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, ati láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ó lágbára ní ọ̀nà jíjìn réré; wọn yóo fi idà wọn rọ ọkọ́, wọn yóo sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé; àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́, wọn kò sì ní kọ́ ogun jíjà mọ́. Ṣugbọn olukuluku yóo jókòó lábẹ́ àjàrà rẹ̀, ati lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kò sì ní sí ẹni tí yóo dẹ́rùbà wọ́n; nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó sọ bẹ́ẹ̀. Olukuluku orílẹ̀-èdè a máa rìn ní ọ̀nà tí oriṣa rẹ̀ là sílẹ̀, ṣugbọn ọ̀nà OLUWA tí Ọlọrun wa là sílẹ̀ ni àwa yóo máa tọ̀ títí laelae. OLUWA ní, “Nígbà tí ó bá yá, n óo kó gbogbo àwọn arọ jọ, n óo kó àwọn tí mo ti túká jọ, ati àwọn tí mo ti pọ́n lójú. N óo dá àwọn arọ sí, kí wọ́n lè wà lára àwọn eniyan Israẹli tí wọ́n ṣẹ́kù, àwọn tí a túká yóo sì di orílẹ̀-èdè ńlá; OLUWA yóo sì jọba lórí wọn ní òkè Sioni láti ìsinsìnyìí lọ ati títí laelae.” Jerusalẹmu, ìwọ ilé ìṣọ́ agbo aguntan Sioni, ilé ọba rẹ àtijọ́ yóo pada sọ́dọ̀ rẹ, a óo dá ìjọba pada sí Jerusalẹmu. Kí ló dé, tí ò ń pariwo bẹ́ẹ̀? Ṣé ẹ kò ní ọba ni? Tabi ẹ kò ní olùdámọ̀ràn mọ́, ni ìrora fi mu yín bí obinrin tí ń rọbí? Ẹ máa yí nílẹ̀, kí ẹ sì máa kérora bí obinrin tí ń rọbí, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu; nítorí pé ẹ gbọdọ̀ jáde ní ìlú yín wàyí, ẹ óo lọ máa gbé inú pápá; ẹ óo lọ sí Babiloni. Ibẹ̀ ni a óo ti gbà yín là, níbẹ̀ ni OLUWA yóo ti rà yín pada kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín. Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè dojú ìjà kọ yín nisinsinyii, wọ́n sì ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á sọ Sioni di aláìmọ́, kí á sì dójúlé e.” Ṣugbọn àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi kò mọ èrò OLUWA, ìpinnu rẹ̀ kò sì yé wọn, pé ó ti kó wọn jọ láti pa wọ́n bí ẹni pa ọkà ní ibi ìpakà. Ẹ dìde kí ẹ tẹ àwọn ọ̀tá yín mọ́lẹ̀, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu! Nítorí n óo mú kí ìwo rẹ lágbára bí irin, pátákò ẹsẹ̀ rẹ yóo sì dàbí idẹ; o óo fọ́ ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè túútúú, o óo sì ya ọrọ̀ wọn sọ́tọ̀ fún OLUWA, nǹkan ìní wọn yóo jẹ́ ti OLUWA àgbáyé. Nisinsinyii, a ti fi odi yi yín ká, ogun sì ti dótì wá; wọ́n fi ọ̀pá na olórí Israẹli ní ẹ̀rẹ̀kẹ́. OLUWA ní, “Ṣugbọn, ìwọ Bẹtilẹhẹmu ní Efurata, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o kéré láàrin gbogbo ẹ̀yà Juda, sibẹ láti inú rẹ ni ẹni tí yóo jẹ́ aláṣẹ Israẹli yóo ti jáde wá fún mi, ẹni tí ìran tí ó ti ṣẹ̀ jẹ́ ti ayérayé, tí ó ti wà láti ìgbà laelae.” Nítorí náà, OLUWA yóo kọ àwọn eniyan rẹ̀ sílẹ̀ títí tí ẹni tí ń rọbí yóo fi bímọ; nígbà náà ni àwọn arakunrin rẹ̀ yòókù yóo pada sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli. Yóo dìde, yóo sì mójútó àwọn eniyan rẹ̀ pẹlu agbára OLUWA, àní, ninu ọláńlá orúkọ OLUWA Ọlọrun rẹ̀. Wọn óo máa gbé ní àìléwu, nítorí yóo di ẹni ńlá jákèjádò gbogbo ayé. Alaafia yóo sì wà, òun gan-an yóo sì jẹ́ ẹni alaafia. Nígbà tí àwọn ará Asiria bá wá gbógun tì wá, tí wọ́n bá sì wọ inú ilẹ̀ wa, a óo rán àwọn olórí wa ati àwọn akikanju láàrin wa láti bá wọn jà. Idà ni wọn yóo fi máa ṣe àkóso ilẹ̀ Asiria ati ilẹ̀ Nimrodu; wọn yóo sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Asiria, nígbà tí wọ́n bá wọ inú ilẹ̀ wa tí wọ́n sì gbógun tì wá. Àwọn ọmọ Israẹli yòókù yóo wà láàrin ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, bí ìrì láti ọ̀dọ̀ OLUWA wá, ati bí ọ̀wààrà òjò lára koríko, tí kò ti ọwọ́ eniyan wá. Àwọn ọmọ Israẹli yòókù yóo wà láàrin àwọn orílẹ̀-èdè ati ọ̀pọ̀ eniyan, bíi kinniun láàrin àwọn ẹranko igbó, bíi ọ̀dọ́ kinniun láàrin agbo-aguntan, tí ó jẹ́ pé bí ọwọ́ rẹ̀ bá tẹ ẹran, yóo fà á ya, kò sì ní sí ẹni tí yóo lè gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. O óo lágbára ju àwọn ọ̀tá rẹ lọ, a óo sì pa wọ́n run. Ní ọjọ́ náà, n óo pa àwọn ẹṣin yín run, n óo sì run gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun yín. N óo pa àwọn ìlú tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ yín run, n óo sì wó ibi ààbò yín lulẹ̀. N óo pa àwọn oṣó run ní ilẹ̀ yín, ẹ kò sì ní ní aláfọ̀ṣẹ kankan mọ́. N óo run àwọn ère ati àwọn òpó oriṣa yín, ẹ kò sì ní máa bọ iṣẹ́ ọwọ́ yín mọ́. N óo run àwọn ère oriṣa Aṣera láàrin yín, n óo sì run àwọn ìlú yín. Ninu ibinu ati ìrúnú mi, n óo gbẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò pa àṣẹ mi mọ́. Ẹ gbọ́ ohun tí Ọlọrun sọ: Ẹ dìde, kí ẹ ro ẹjọ́ yín níwájú àwọn òkè ńlá, kí ẹ sì jẹ́ kí àwọn òkè kéékèèké gbọ́ ohùn yín. Ẹ̀yin òkè, ati ẹ̀yin ìpìlẹ̀ ayérayé, ẹ gbọ́ ẹjọ́ OLUWA, nítorí ó ń bá àwọn eniyan rẹ̀ rojọ́, yóo sì bá Israẹli jà. Ọlọrun ní, “Ẹ̀yin eniyan mi, kí ni mo fi ṣe yín? Kí ni mo ṣe tí ọ̀rọ̀ mi fi su yín? Ẹ dá mi lóhùn. Èmi ni mo sá mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, tí mo rà yín pada kúrò lóko ẹrú; tí mo rán Mose, Aaroni ati Miriamu láti ṣáájú yín. Ẹ̀yin eniyan mi, ẹ ranti ète tí Balaki, ọba Moabu pa si yín, ati ìdáhùn tí Balaamu, ọmọ Beori, fún un. Ẹ ranti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ninu ìrìn àjò yín láti Ṣitimu dé Giligali, kí ẹ lè mọ iṣẹ́ ìgbàlà tí OLUWA ṣe.” Kí ni n óo mú wá fún OLUWA, tí n óo fi rẹ ara mi sílẹ̀ níwájú Ọlọrun, ẹni gíga? Ṣé kí n wá siwaju rẹ̀ pẹlu ẹbọ sísun ni tabi pẹlu ọ̀dọ́ mààlúù ọlọ́dún kan? Ǹjẹ́ inú OLUWA yóo dùn bí mo bá mú ẹgbẹẹgbẹrun aguntan wá, pẹlu ẹgbẹgbaarun-un garawa òróró olifi? Ṣé kí n fi àkọ́bí mi ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ mi, àní kí n fi ọmọ tí mo bí rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mi? A ti fi ohun tí ó dára hàn ọ́, ìwọ eniyan. Kí ni OLUWA fẹ́ kí o ṣe, ju pé kí o jẹ́ olótìítọ́ lọ, kí o máa ṣàánú eniyan, kí o sì máa rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹlu Ọlọrun rẹ? Ẹ gbọ́ ẹ̀yin ará, ati àpéjọ gbogbo ìlú; ohun tí ó ti dára ni pé kí eniyan bẹ̀rù OLUWA; Ǹjẹ́ mo lè gbàgbé ìṣúra aiṣododo tí ó wà ninu ilé àwọn eniyan burúkú, ati òṣùnwọ̀n èké ó jẹ́ ohun ìfibú? Báwo ni mo ṣe lè dáríjì àwọn tí ń lo òṣùnwọ̀n èké; tí àpò wọn sì kún fún ìwọ̀n tí kò péye? Àwọn ọlọ́rọ̀ yín kún fún ìwà ipá; òpùrọ́ ni gbogbo àwọn ará ìlú, ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn sì kún ẹnu wọn. Nítorí náà, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí pa yín run n óo sọ ìlú yín di ahoro nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín. Ẹ óo jẹun, ṣugbọn ẹ kò ní yó, ebi yóo sì túbọ̀ máa pa yín, ẹ óo kó ọrọ̀ jọ, ṣugbọn kò ní dúró lọ́wọ́ yín, ogun ni yóo sì kó ohun tí ẹ kó jọ lọ. Ẹ óo fúnrúgbìn, ṣugbọn ẹ kò ní kórè rẹ̀; ẹ óo ṣe òróró olifi, ṣugbọn ẹ kò ní rí i fi para; ẹ óo ṣe ọtí waini, ṣugbọn ẹ kò ní rí i mu. Nítorí pé ẹ̀ ń tẹ̀lé ìlànà ọba Omiri, ati ti ìdílé ọba Ahabu, ẹ sì ti tẹ̀lé ìmọ̀ràn wọn; kí n lè sọ ìlú yín di ahoro, kí àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀ sì di ohun ẹ̀gàn; kí àwọn eniyan sì máa fi yín ṣẹ̀sín. Mo gbé! Nítorí pé, mo dàbí ìgbà tí wọn ti kórè èso àkókò ẹ̀ẹ̀rùn tán, tí wọ́n ti ká èso àjàrà tán; tí kò sí èso àjàrà mọ́ fún jíjẹ, tí kò sì sí àkọ́so èso ọ̀pọ̀tọ́ tí mo fẹ́ràn mọ́. Olóòótọ́ ti tán lórí ilẹ̀ ayé, kò sí olódodo mọ́ láàrin àwọn eniyan; gbogbo wọn ń wá ọ̀nà ìpànìyàn, olukuluku ń fi àwọ̀n dọdẹ arakunrin rẹ̀. Wọ́n mọ iṣẹ́ ibi í ṣe dáradára; àwọn ìjòyè ati àwọn onídàájọ́ wọn ń bèèrè àbẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn eniyan ńlá ń sọ èrò burúkú tí ó wà lọ́kàn wọn jáde; wọ́n sì ń pa ìmọ̀ wọn pọ̀. Ẹni tí ó sàn jùlọ ninu wọn dàbí ẹ̀gún, ẹni tí ó jẹ́ olódodo jùlọ láàrin wọn sì dàbí ẹ̀gún ọ̀gàn. Ọjọ́ ìjìyà tí àwọn wolii wọn kéde ti dé; ìdàrúdàpọ̀ wọn sì ti kù sí dẹ̀dẹ̀. Má gbára lé aládùúgbò rẹ, má sì ṣe gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rẹ́; ṣọ́ra nípa ohun tí o óo máa bá iyawo rẹ sọ. Nítorí ọmọkunrin ń tàbùkù baba rẹ̀, ọmọbinrin sì ń dìde sí ìyá rẹ̀, iyawo ń gbógun ti ìyá ọkọ rẹ̀; àwọn ará ilé ẹni sì ni ọ̀tá ẹni. Ṣugbọn ní tèmi, n óo máa wo ojú OLUWA, n óo dúró de Ọlọrun ìgbàlà mi; Ọlọrun mi yóo sì gbọ́ tèmi. Má yọ̀ mí, ìwọ ọ̀tá mi; bí mo bá ṣubú, n óo dìde; bí mo bá sì wà ninu òkùnkùn, OLUWA yóo jẹ́ ìmọ́lẹ̀ mi. N óo fara da ìyà tí OLUWA bá fi jẹ mí Nítorí pé mo ti ṣẹ̀ ẹ́, títí tí yóo fi gbèjà mi, tí yóo sì dá mi láre. Yóo mú mi wá sinu ìmọ́lẹ̀; ojú mi yóo sì rí ìdáǹdè rẹ̀. Nígbà náà ni àwọn ọ̀tá mi yóo rí i, ojú yóo sì ti ẹni tí ń pẹ̀gàn mi pé, níbo ni OLUWA Ọlọrun mi wà? N óo fi ojú mi rí i; òun náà yóo wá di àtẹ̀mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ ní ìta gbangba. Ní ọjọ́ tí a óo bá mọ odi ìlú yín, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ọjọ́ náà ni a óo sún ààlà yín siwaju. Ní ọjọ́ náà, àwọn eniyan yóo wá sọ́dọ̀ yín láti ilẹ̀ Asiria títí dé ilẹ̀ Ijipti, láti ilẹ̀ Ijipti títí dé bèbè odò Yufurate, láti òkun dé òkun, ati láti òkè ńlá dé òkè ńlá. Ṣugbọn ayé yóo di ahoro nítorí ìwàkiwà àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀; àní nítorí iṣẹ́kíṣẹ́ ọwọ́ wọn. OLUWA, fi ọ̀pá rẹ tọ́ àwọn eniyan rẹ, àní agbo aguntan ìní rẹ, tí wọn ń dá gbé ninu igbó, láàrin ilẹ̀ ọgbà; jẹ́ kí wọ́n máa jẹko ní Baṣani ati ní Gileadi bí ìgbà àtijọ́. N óo fi ohun ìyanu hàn wọ́n gẹ́gẹ́ bíi ti ìgbà tí ẹ jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo rí i, ojú agbára wọn yóo tì wọ́n; wọn óo pa ẹnu wọn mọ́; etí wọn óo sì di; wọn óo fi ẹnu gbo ilẹ̀ bí ìgbín, pẹlu ìbẹ̀rù ati ìwárìrì ni wọn yóo jáde bí ejò, láti ibi ààbò wọn; ninu ìbẹ̀rù, wọn óo pada tọ OLUWA Ọlọrun wá, ẹ̀rù rẹ yóo sì máa bà wọ́n. Ta ló dàbí rẹ, Ọlọrun, tí ó ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan, tí ó sì ń fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan ìní rẹ̀ yòókù, ibinu rẹ kì í wà títí lae, nítorí pé a máa dùn mọ́ ọ láti fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn. O óo tún ṣàánú wa, o óo sì fẹsẹ̀ tẹ ẹ̀ṣẹ̀ wa ní àtẹ̀parẹ́. O óo sọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa sí ìsàlẹ̀ òkun. O óo fi òtítọ́ inú hàn sí Jakọbu, o óo sì fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí Abrahamu, gẹ́gẹ́ bí o ti búra fún àwọn baba wa láti ìgbà àtijọ́. Ọ̀rọ̀ OLUWA nìyí; tí a kọ sinu ìwé ìran tí Nahumu ará Elikoṣi rí nípa ìlú Ninefe. OLUWA tíí jowú tíí sìí máa gbẹ̀san ni Ọlọrun. OLUWA a máa gbẹ̀san, a sì máa bínú. OLUWA a máa gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀, a sì máa fi ìrúnú rẹ̀ pamọ́ de àwọn ọ̀tá rẹ̀. OLUWA kì í tètè bínú; ó lágbára lọpọlọpọ, kì í sìí dá ẹni tí ó bá jẹ̀bi láre. Ipa ọ̀nà rẹ̀ wà ninu ìjì ati ẹ̀fúùfù líle, awọsanma sì ni eruku ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó bá òkun wí, ó mú kí ó gbẹ, ó sì mú kí gbogbo odò gbẹ pẹlu; koríko ilẹ̀ Baṣani ati ti òkè Kamẹli gbẹ, òdòdó ilẹ̀ Lẹbanoni sì rẹ̀. Àwọn òkè ńláńlá mì tìtì níwájú rẹ̀, àwọn òkè kéékèèké sì yọ́. Ilẹ̀ di asán níwájú rẹ̀, ayé ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ di òfo. Bí ó bá ń bínú ta ló lè dúró? Ta ló lè farada ibinu gbígbóná rẹ̀? Ìrúnú rẹ̀ a máa ru jáde bí ahọ́n iná, a sì máa fọ́ àwọn àpáta níwájú rẹ̀. OLUWA ṣeun, òun ni ibi ààbò ní ọjọ́ ìdààmú; ó sì mọ àwọn tí wọn ń sálọ sọ́dọ̀ rẹ̀ fún ààbò. Bí odò tí ó kún bo bèbè rẹ̀ ni yóo ṣe mú ìparun bá àwọn ọ̀tá rẹ̀; yóo sì lépa àwọn ọ̀tá rẹ̀ bọ́ sí inú òkùnkùn. Èrò ibi wo ni ẹ̀ ń gbà sí OLUWA? Yóo wulẹ̀ pa yín run patapata ni; kò sì sí ẹni tí OLUWA yóo gbẹ̀san lára rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan tí yóo lè ṣẹ̀ ẹ́ lẹẹkeji. Wọn yóo jóná bí igbó ẹlẹ́gùn-ún tí ó dí, àní bíi koríko gbígbẹ. Ṣebí ọ̀kan ninu yín ni ó ń gbìmọ̀ burúkú sí OLUWA, tí ó sì ń fúnni ní ìmọ̀ràn burúkú? OLUWA wí pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Siria lágbára, tí wọ́n sì pọ̀, a óo pa wọ́n run, wọn yóo sì parẹ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti jẹ ẹ̀yin ọmọ Juda níyà tẹ́lẹ̀, n kò ní jẹ yín níyà mọ́. N óo bọ́ àjàgà Asiria kúrò lọ́rùn yín, n óo sì já ìdè yín.” OLUWA ti pàṣẹ nípa Asiria, pé: “A kò ní ranti orúkọ rẹ mọ́, ìwọ ilẹ̀ Asiria, n óo run àwọn ère tí ẹ̀yin ará Asiria gbẹ́, ati àwọn tí ẹ dà, tí wọ́n wà ní ilé oriṣa rẹ, n óo gbẹ́ ibojì rẹ, nítorí ẹlẹ́gbin ni ọ́.” Wo ẹsẹ̀ ẹni tí ó ń mú ìyìn rere wá lórí àwọn òkè ńláńlá, ẹni tí ń kéde alaafia! Ẹ máa ṣe àwọn àjọ̀dún yín, ẹ̀yin ará Juda, kí ẹ sì san àwọn ẹ̀jẹ́ yín, nítorí ẹni ibi kò ní gbógun tì yín mọ́, a ti pa á run patapata. Atúniká ti gbógun tì ọ́, ìwọ Ninefe. Yan eniyan ṣọ́ ibi ààbò; máa ṣọ́nà, di àmùrè rẹ, kí o sì múra ogun. (Nítorí OLUWA ti ṣetán láti dá ògo Jakọbu pada bí ògo Israẹli, nítorí àwọn tí wọn ń kóni lẹ́rú ti kó wọn, wọ́n sì ti ba àwọn ẹ̀ka wọn jẹ́.) Pupa ni asà àwọn akọni rẹ̀, ẹ̀wù pupa ni àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wọ̀ Kẹ̀kẹ́ ogun wọn ń kọ mànà bí ọwọ́ iná; nígbà tí wọ́n tò wọ́n jọ, àwọn ẹṣin wọn ń yan. Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun ń dà wọ ìgboro pẹlu ariwo, wọ́n ń sáré sókè sódò ní gbàgede; wọ́n mọ́lẹ̀ yòò bí iná ìtùfù, wọ́n ń kọ mànà bí mànàmáná. Ó pe àwọn ọ̀gágun rẹ̀ jọ, wọ́n sì ń fẹsẹ̀ kọ bí wọ́n ti ń lọ, wọ́n yára lọ sí ibi odi, wọ́n sì fi asà dira ogun. Àwọn ìlẹ̀kùn odò ṣí sílẹ̀, ìdàrúdàpọ̀ wà láàfin. A tú ayaba sí ìhòòhò, a sì mú un lọ sí ìgbèkùn, àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ ń dárò rẹ̀, wọ́n káwọ́ lérí, wọ́n ń rin bí oriri. Ìlú Ninefe dàbí adágún odò tí omi rẹ̀ ti ṣàn lọ. Wọ́n ń kígbe pé, “Ẹ dúró! Ẹ dúró!” Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó yíjú pada. Ẹ kó fadaka, ẹ kó wúrà! Ìlú náà kún fún ìṣúra, ati àwọn nǹkan olówó iyebíye. A ti pa Ninefe run! Ó ti dahoro! Ọkàn àwọn eniyan ti dàrú, orúnkún wọn ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, ìrora dé bá ọpọlọpọ, gbogbo ojú wọn sì rẹ̀wẹ̀sì. Níbo ni ìlú tí ó dàbí ihò àwọn kinniun wà? Tí ó rí bí ibùgbé àwọn ọ̀dọ́ kinniun? Ibi tí kinniun ń gbé oúnjẹ rẹ̀ lọ, tí àwọn ọmọ rẹ̀ wà, tí kò sí ẹni tí ó lè dà wọ́n láàmú? Akọ kinniun a máa fa ẹran ya fún àwọn ọmọ rẹ̀, a sì máa lọ́ ẹran lọ́rùn pa fún àwọn abo rẹ̀; a máa kó ẹran tí ó bá pa ati èyí tí ó fàya sinu ihò rẹ̀. OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Wò ó! Mo ti dójú lé ọ. N óo dáná sun kẹ̀kẹ́ ogun rẹ, n óo sì fi idà pa àwọn ọmọ ogun rẹ. Gbogbo ohun tí o ti gbà lọ́wọ́ àwọn ẹlòmíràn ni n óo gbà pada lọ́wọ́ rẹ; a kò sì ní gbọ́ ohùn àwọn iranṣẹ rẹ mọ́.” Ìlú tí ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ gbé! Ìlú tí ó kún fún irọ́ ati ìkógun, tí àwọn adigunjalè kò fi ìgbà kan dáwọ́ dúró níbẹ̀! Pàṣán ń ró, ẹṣin ń yan, kẹ̀kẹ́ ogun ń pariwo! Àwọn ẹlẹ́ṣin ti múra ìjà pẹlu idà ati ọ̀kọ̀ tí ń kọ mànà. Ọpọlọpọ ni wọ́n ti pa sílẹ̀, òkítì òkú kúnlẹ̀ lọ kítikìti; òkú sùn lọ bẹẹrẹ láìníye, àwọn eniyan sì ń kọlu àwọn òkú bí wọn tí ń lọ! Nítorí ọpọlọpọ ìwà àgbèrè Ninefe, tí wọ́n fanimọ́ra, ṣugbọn tí wọ́n kún fún òògùn olóró, ni gbogbo ìjìyà yìí ṣe dé bá a; nítorí ó ń fi ìwà àgbèrè rẹ̀ tan àwọn orílẹ̀-èdè jẹ, ó sì ń fi òògùn rẹ̀ mú àwọn eniyan. OLUWA àwọn ọmọ ogun ní: “Wò ó! Mo ti gbógun tì ọ́, Ninefe, n óo ká aṣọ kúrò lára rẹ, n óo fi bò ọ́ lójú; n óo tú ọ sí ìhòòhò lójú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn yóo rí ìhòòhò rẹ ojú yóo sì tì ọ́. N óo mú ẹ̀gbin bá ọ n óo fi àbùkù kàn ọ́; n óo sì sọ ọ́ di ẹlẹ́yà ati ẹni àpéwò. Ẹnu yóo ya gbogbo àwọn tí ó bá wò ọ́, wọn yóo máa wí pé: ‘Ninefe ti di ahoro; ta ni yóo dárò rẹ̀? Níbo ni n óo ti rí olùtùnú fún ọ?’ ” Ṣé ìwọ Ninefe sàn ju ìlú Tebesi lọ, ìlú tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ odò Naili, tí omi yíká, tí ó fi òkun ṣe ààbò, tí ó sì fi omi ṣe odi rẹ̀? Etiopia ati Ijipti ni agbára rẹ̀ tí kò lópin; Puti ati Libia sì ni olùrànlọ́wọ́ rẹ̀. Sibẹsibẹ àwọn ọ̀tá kó o lọ sí ìgbèkùn, wọ́n ṣán àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀, wọ́n pa wọ́n ní ìpakúpa ní gbogbo àwọn ìkóríta wọn. Wọ́n ṣẹ́ gègé lórí àwọn ọlọ́lá ibẹ̀, wọ́n sì fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ de àwọn eniyan pataki wọn. Ninefe, ìwọ pàápàá yóo mu ọtí yó, o óo máa ta gbọ̀n- ọ́ngbọ̀n-ọ́n; o óo sì máa wá ààbò nítorí àwọn ọ̀tá rẹ. Gbogbo ibi ààbò rẹ yóo dàbí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí àkọ́so èso rẹ̀ pọ́n bí wọn bá ti gbọ̀n ọ́n, bẹ́ẹ̀ ni èso rẹ̀ yóo máa jábọ́ sí ẹnu ẹni tí yóo jẹ ẹ́. Wò ó! Àwọn ọmọ ogun rẹ dàbí obinrin! Gbogbo ẹnubodè rẹ wà ní ṣíṣí sílẹ̀ fún àwọn ọ̀tá rẹ; iná sì ti jó gbogbo ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn bodè rẹ. Ẹ pọn omi sílẹ̀ de àkókò tí ogun yóo dótì yín, ẹ ṣe ibi ààbò yín kí ó lágbára; ẹ lọ sí ibi ilẹ̀ alámọ̀, ẹ gún amọ̀, kí ẹ fi ṣe bíríkì! Ibẹ̀ ni iná yóo ti jó yín run, idà yóo pa yín lọ bí eṣú. Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ pọ̀ bí eṣú! O ti wá kún àwọn oníṣòwò rẹ, wọ́n sì pọ̀ ju ìràwọ̀ ojú ọ̀run lọ! Ṣugbọn wọ́n ti na ìyẹ́ wọn bí eṣú, wọ́n sì fò lọ. Àwọn olórí yín dàbí tata, àwọn akọ̀wé yín sì dàbí ọ̀wọ́ eṣú, tíí bà sórí odi nígbà òtútù, nígbà tí oòrùn bá yọ wọn a fò lọ; kò sì ní sí ẹni tí yóo mọ ibi tí wọ́n lọ. Àwọn olùṣọ́ rẹ ń sùn, ìwọ ọba Asiria, àwọn ọlọ́lá rẹ sì ń tòògbé; Àwọn eniyan rẹ fọ́nká lórí àwọn òkè, láìsí ẹni tí yóo gbá wọn jọ. Kò sí ẹni tí yóo wo ọgbẹ́ rẹ sàn nítorí egbò rẹ pọ̀. Àwọn tí wọ́n bá gbọ́ ìròyìn rẹ yóo pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí, nítorí kò sí ẹni tí kò tíì faragbá ninu ìwà burúkú rẹ. Ìran tí Ọlọrun fihan wolii Habakuku nìyí. OLUWA, yóo ti pẹ́ tó, tí n óo máa ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́; tí o kò sì ní dá mi lóhùn? Tí n óo máa ké pé, “Wo ìwà ipá!” tí o kò sì ní gba olúwarẹ̀ sílẹ̀? Kí ló dé tí o fi ń jẹ́ kí n máa rí àwọn nǹkan tí kò tọ́, tí o jẹ́ kí n máa rí ìyọnu? Ìparun ati ìwà ipá wà níwájú mi, ìjà ati aáwọ̀ sì wà níbi gbogbo. Òfin kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìdájọ́ òdodo. Àwọn ẹni ibi dòòyì ká olódodo, wọ́n sì ń yí ìdájọ́ òdodo po. Ọlọrun ní: “Wo ààrin àwọn orílẹ̀-èdè yíká, O óo rí ohun ìjọjú yóo sì yà ọ́ lẹ́nu. Nítorí mò ń ṣe nǹkan ìyanu kan ní àkókò rẹ, tí o kò ní gbàgbọ́ bí wọ́n bá sọ fún ọ. Wò ó! N óo gbé àwọn ará Kalidea dìde, orílẹ̀-èdè tí ó yára, tí kò sì ní àánú; àwọn tí wọ́n la ìbú ayé já, tí wọn ń gba ilẹ̀ onílẹ̀ káàkiri. Ìrísí wọn bani lẹ́rù; wọ́n ń fi ọlá ńlá wọn ṣe ìdájọ́ bí ó ti wù wọ́n. “Àwọn ẹṣin wọn yára ju àmọ̀tẹ́kùn lọ, wọ́n burú ju ìkookò tí ebi ń pa ní àṣáálẹ́ lọ. Pẹlu ìgbéraga ni àwọn ẹlẹ́ṣin wọn máa ń gun ẹṣin wọn lọ. Dájúdájú, ọ̀nà jíjìn ni àwọn ẹlẹ́ṣin wọn ti ń wá; wọn a fò, bí idì tí ń sáré sí oúnjẹ. “Tìjàtìjà ni gbogbo wọn máa ń rìn, ìpayà á bá gbogbo eniyan bí wọ́n bá ti ń súnmọ́ tòsí. Wọn a kó eniyan ní ìgbèkùn, bí ẹni kó yanrìn nílẹ̀. Wọn a máa fi àwọn ọba ṣe ẹlẹ́yà, wọn a sì sọ àwọn ìjòyè di àmúṣèranwò. Wọn a máa fi àwọn ìlú olódi ṣe ẹlẹ́yà, nítorí òkítì ni wọ́n mọ sí ara odi wọn, wọn a sì gbà wọ́n. Wọn a fẹ́ wá bí ìjì, wọn a sì tún fẹ́ lọ, àwọn olubi eniyan, tí agbára wọn jẹ́ ọlọrun wọn.” OLUWA, ṣebí láti ayérayé ni o ti wà? Ọlọrun mi, Ẹni Mímọ́ mi, a kò ní kú. OLUWA, ìwọ ni o yan àwọn ará Babiloni gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́. Ìwọ Àpáta, ni o gbé wọn kalẹ̀ bíi pàṣán, láti jẹ wá níyà. Mímọ́ ni ojú rẹ, o kò lè wo ibi o kò lè gba ohun tí kò tọ́. Kí ló wá dé tí o fi ń wo àwọn ọ̀dàlẹ̀, tí o sì dákẹ́, tí ò ń wo àwọn ẹni ibi níran tí wọn ń run àwọn tí wọ́n ṣe olódodo jù wọ́n lọ. Nítorí o ti jẹ́ kí ọmọ eniyan dàbí ẹja inú òkun, ati bí àwọn kòkòrò tí wọn ń rìn nílẹ̀, tí wọn kò ní olórí. Ọ̀tá fi ìwọ̀ fa gbogbo wọn sókè, ó sì fi àwọ̀n rẹ̀ kó wọn jáde. Ó kó wọn papọ̀ sinu àwọ̀n rẹ̀, Nítorí náà ó ń yọ̀, inú rẹ̀ sì dùn. Nítorí náà a máa bọ àwọ̀n rẹ̀. A sì máa fi turari rúbọ sí àwọ̀n rẹ̀ ńlá; nítorí a máa rò lọ́kàn rẹ̀ pé, àwọ̀n òun ni ó ń jẹ́ kí òun gbádùn ayé tí òun sì fi ń rí oúnjẹ aládùn jẹ. Ṣé gbogbo ìgbà ni àwọn eniyan yóo máa bọ́ sinu àwọ̀n rẹ̀ ni? Ṣé títí lae ni yóo sì máa pa àwọn orílẹ̀-èdè run láìláàánú? N óo dúró sí ibìkan lórí ilé-ìṣọ́, n óo máa wòran. N óo dúró, n óo máa retí ohun tí yóo sọ fún mi, ati irú èsì tí èmi náà óo fún un. OLUWA dá mi lóhùn, ó ní: “Kọ ìran yìí sílẹ̀; kọ ọ́ sórí tabili kí ó hàn ketekete, kí ó lè rọrùn fún ẹni tí ń sáré lọ láti kà á. Kọ ọ́ sílẹ̀, nítorí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú ni; ọjọ́ náà kò ní pẹ́ dé, ohun tí o rí kì í ṣe irọ́, dájúdájú yóo ṣẹ. Bí ó bá dàbí ẹni pé ó ń pẹ́, ìwọ ṣá dúró kí o máa retí rẹ̀, dájúdájú, yóo ṣẹ, láìpẹ́. Wò ó! Ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò ṣe déédéé ninu OLUWA yóo ṣègbé; ṣugbọn olódodo yóo wà láàyè nípa igbagbọ.” Ọrọ̀ a máa tan eniyan jẹ; onigbeeraga kò sì ní wà láàyè pẹ́. Ojúkòkòrò rẹ̀ dàbí isà òkú; nǹkan kì í sì í tó o, àfi bí ikú. Ó gbá gbogbo orílẹ̀-èdè jọ fún ara rẹ̀, ó sì sọ gbogbo eniyan di ti ara rẹ̀. Ǹjẹ́ gbogbo àwọn eniyan wọnyi kò ní máa kẹ́gàn rẹ̀, kí wọ́n sì máa fi ṣe ẹlẹ́yà pé, “Ègbé ni fún ẹni tí ń kó ohun tí kì í ṣe tirẹ̀ jọ. Ìgbà wo ni yóo ṣe èyí dà, tí yóo máa gba ìdógò lọ́wọ́ àwọn onígbèsè rẹ̀ kiri?” Ǹjẹ́ àwọn onígbèsè rẹ kò ní dìde sí ọ lójijì, kí àwọn tí wọn yóo dẹ́rùbà ọ́ sì jí dìde, kí o wá di ìkógun fún wọn? Nítorí pé ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ni o ti kó lẹ́rú, gbogbo àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ni wọn yóo sì kó ìwọ náà lẹ́rú, nítorí ẹ̀jẹ̀ àwọn eniyan tí o ti pa, ati ìwà ipá tí o hù lórí ilẹ̀ ayé, ati èyí tí o hù sí oríṣìíríṣìí ìlú ati àwọn tí wọn ń gbé inú wọn. Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi ipá kó èrè burúkú jọ tí ẹ óo fi kọ́ ibùgbé sí ibi gíga, kí nǹkan burúkú kankan má baà ṣẹlẹ̀ si yín! O ti kó ìtìjú bá ilé rẹ nítorí ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè tí o parun; ìwọ náà ti wá pàdánù ẹ̀mí rẹ. Nítorí òkúta yóo kígbe lára ògiri, igi ìdábùú òpó ilé yóo sì fọhùn pẹlu. Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi ìwà ìpànìyàn kó ìlú jọ, tí ẹ fi ìwà ọ̀daràn tẹ ìlú dó. Wò ó, ṣebí ìkáwọ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó wà, pé kí orílẹ̀-èdè kan ṣe làálàá tán, kí iná sì jó gbogbo rẹ̀ ní àjórun, kí wahala orílẹ̀-èdè náà sì já sí asán. Nítorí ayé yóo kún fún ìmọ̀ ògo OLUWA, gẹ́gẹ́ bí omi ti kún inú òkun. Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ fi ibinu fún aládùúgbò yín ní ọtí mu, tí ẹ jẹ́ kí inú wọn ru, kí ẹ lè rí ìhòòhò wọn. Ìtìjú ni yóo bò yín dípò ògo. Ẹ máa mu àmupara kí ẹ sì máa ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n, ife ìjẹníyà tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún OLUWA yóo kàn yín, ìtìjú yóo sì bo ògo yín. Ibi tí ó dé bá Lẹbanoni yóo bò yín mọ́lẹ̀; ìparun àwọn ẹranko yóo dẹ́rùbà yín, nítorí ìpànìyàn ati ibi tí ẹ ṣe sí ayé, sí àwọn ìlú ati àwọn tí wọn ń gbé inú wọn. Èrè kí ni ó wà ninu ère? Ère irin lásánlàsàn, tí eniyan ṣe, tí ń kọ́ni ní irọ́ pípa. Nítorí ẹni tí ó ṣe wọ́n gbẹ́kẹ̀lé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ère tí ó gbẹ́ tán tí kò lè sọ̀rọ̀! Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sọ fún ohun tí a fi igi gbẹ́, pé kí ó dìde; ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sọ fún òkúta tí kò lè sọ̀rọ̀, pé kí ó gbéra nílẹ̀. Ǹjẹ́ eléyìí lè rí ìran kankan? Wò ó! Wúrà ati fadaka ni wọ́n yọ́ lé e, kò sì ní èémí ninu rárá. Ṣugbọn OLUWA ń bẹ ninu tẹmpili mímọ́ rẹ̀, kí gbogbo ayé parọ́rọ́ níwájú rẹ̀. Adura tí wolii Habakuku kọ lórin nìyí: OLUWA, mo ti gbọ́ òkìkí rẹ, mo sì bẹ̀rù iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Gbogbo bí ò ó tíí ṣe tí à ń gbọ́; tún wá ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tiwa; sì ranti àánú ní àkókò ibinu rẹ. OLUWA wá láti Temani, Ẹni Mímọ́ sì wá láti òkè Parani. Ògo rẹ̀ bo ojú ọ̀run, gbogbo ayé sì kún fún ìyìn rẹ̀. Dídán rẹ̀ dàbí ọ̀sán gangan, ìtànṣán ń ti ọwọ́ rẹ̀ jáde; níbẹ̀ ni ó fi agbára rẹ̀ pamọ́ sí. Àjàkálẹ̀ àrùn ń lọ níwájú rẹ̀, ìyọnu sì ń tẹ̀lé e lẹ́yìn pẹ́kípẹ́kí. Ó dúró, ó wọn ayé; Ó wo ayé, ó sì mi àwọn orílẹ̀-èdè tìtì; àwọn òkè ńláńlá ayérayé túká, àwọn òkè àtayébáyé sì wọlẹ̀. Ọ̀nà àtayébáyé ni ọ̀nà rẹ̀. Mo rí àwọn àgọ́ Kuṣani ninu ìyọnu, àwọn aṣọ ìkélé àwọn ará ilẹ̀ Midiani sì ń mì tìtì. OLUWA, ṣé àwọn odò ni inú rẹ ń ru sí ni, àbí àwọn ìṣàn omi ni ò ń bínú sí, tabi òkun ni ò ń bá bínú, nígbà tí o bá gun àwọn ẹṣin rẹ, tí o wà ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ? Ìwọ tí ò ń tu àkọ̀ kúrò lára ọrun, tí o fi ọfà lé ọsán ọrun; tí o wá fi omi pín ilẹ̀ ayé. Nígbà tí àwọn òkè ńlá rí ọ, wọ́n wárìrì; àgbàrá omi wọ́ kọjá; ibú òkun pariwo, ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè. Oòrùn ati òṣùpá dúró ní ipò wọn, nígbà tí ọfà rẹ ń já lọ ṣòòrò, tí àwọn ọ̀kọ̀ rẹ náà ń kọ mànà, bí wọ́n ti ń fò lọ. O la ayé kọjá pẹlu ibinu, o sì fi ibinu tẹ àwọn orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀. O jáde lọ láti gba àwọn eniyan rẹ là, láti gba àwọn àyànfẹ́ rẹ là. O wó orí aṣiwaju ilẹ̀ àwọn ẹni ibi wómúwómú, o tú u sí ìhòòhò láti itan dé ọrùn. O fi ọ̀kọ̀ rẹ gún orí àwọn olórí ogun; àwọn tí wọ́n wá bí ìjì líle láti tú wa ká, tí wọn ń yọ̀ bí ẹni tí ń ni talaka lára níkọ̀kọ̀. O fi àwọn ẹṣin rẹ tẹ òkun mọ́lẹ̀; wọ́n tẹ ríru omi mọ́lẹ̀. Mo gbọ́, àyà mi sì lù kìkì, ètè mi gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ nígbà tí mo gbọ́ ìró rẹ̀; egungun mi bẹ̀rẹ̀ sí rà, ẹsẹ̀ mi ń gbọ̀n rìrì nílẹ̀. N óo fi sùúrù dúró jẹ́ẹ́ de ọjọ́ tí ìṣòro yóo dé bá àwọn tí wọ́n kó wa lẹ́rù. Bí igi ọ̀pọ̀tọ́ kò tilẹ̀ rúwé, tí àjàrà kò sì so, tí kò sí èso lórí igi olifi; tí àwọn irúgbìn kò sì so lóko, tí àwọn agbo aguntan run, tí kò sì sí mààlúù ninu agbo mọ́, sibẹsibẹ, n óo yọ̀ ninu OLUWA, n óo yọ̀ ninu Ọlọrun Olùgbàlà mi. Ọlọrun, OLUWA, ni agbára mi; Ó mú kí ẹsẹ̀ mi yá nílẹ̀ bíi ti àgbọ̀nrín, ó mú mi rìn lórí àwọn òkè gíga. (Sí ọ̀gá akọrin; pẹlu àwọn ohun èlò orin olókùn.) Èyí ni iṣẹ́ tí Ọlọrun rán Sefanaya, ọmọ Kuṣi, ọmọ Gedalaya, ọmọ Amaraya, ọmọ Hesekaya ní àkókò ìjọba Josaya, ọmọ Amoni, ọba Juda. OLUWA ní, “N óo pa gbogbo nǹkan tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé run: ati eniyan ati ẹranko, ati gbogbo ẹyẹ, ati gbogbo ẹja. N óo bi àwọn eniyan burúkú ṣubú; n óo pa eniyan run lórí ilẹ̀. “N óo na ọwọ́ ibinu mi sí ilẹ̀ Juda, ati sí àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu. N óo pa gbogbo oriṣa Baali tí ó kù níhìn-ín run, ati gbogbo àwọn babalóòṣà wọn; ati àwọn tí ń gun orí òrùlé lọ láti bọ oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀. Wọ́n ń sin OLUWA wọ́n sì ń fi orúkọ rẹ̀ búra wọ́n sì tún ń fi oriṣa Milikomu búra; àwọn tí wọ́n ti pada lẹ́yìn OLUWA, tí wọn kò wá a, tí wọn kì í sì í wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀.” Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú OLUWA Ọlọrun! Nítorí ọjọ́ OLUWA súnmọ́lé; OLUWA ti ṣètò ẹbọ kan, ó sì ti ya àwọn kan sọ́tọ̀, tí yóo pè wá jẹ ẹ́. Ní ọjọ́ ìrúbọ OLUWA, “N óo fi ìyà jẹ àwọn alákòóso ati àwọn ọmọ ọba, ati àwọn tí ń fi aṣọ orílẹ̀-èdè mìíràn ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́. Ní ọjọ́ náà, n óo jẹ àwọn tí ń fo ẹnu ọ̀nà kọjá bí àwọn abọ̀rìṣà níyà, ati àwọn tí ń fi ìwà ipá, ati olè jíjà kó nǹkan kún ilé oriṣa wọn.” OLUWA ní, “Ní ọjọ́ náà, ariwo ńlá ati ìpohùnréré ẹkún yóo sọ ní Ẹnubodè Ẹja ní Jerusalẹmu; ní apá ibi tí àwọn eniyan ń gbé, ati ariwo bí ààrá láti orí òkè wá. Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Mota, ní Jerusalẹmu; nítorí pé àwọn oníṣòwò ti lọ tán patapata; a ti pa àwọn tí ń wọn fadaka run. “Ní àkókò náà ni n óo tanná wo Jerusalẹmu fínnífínní, n óo jẹ àwọn ọkunrin tí wọ́n rò pé àwọn gbọ́n lójú ara wọn níyà, àwọn tí ń sọ ninu ọkàn wọn pé, ‘kò sí ohun tí Ọlọrun yóo ṣe.’ A óo kó wọn lẹ́rù lọ, a óo sì wó ilé wọn lulẹ̀. Bí wọ́n tilẹ̀ kọ́ ọpọlọpọ ilé, wọn kò ní gbébẹ̀; bí wọ́n sì gbin ọgbà àjàrà, wọn kò ní mu ninu waini rẹ̀.” Ọjọ́ ńlá OLUWA súnmọ́lé, ó súnmọ́ etílé, ó ń bọ̀ kíákíá. Ọjọ́ náà yóo burú tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn akikanju ọkunrin yóo kígbe lóhùn rara. Ọjọ́ ibinu ni ọjọ́ náà yóo jẹ́, ọjọ́ ìpọ́njú ati ìrora, ọjọ́ ìyọnu ati ìparun, ọjọ́ òkùnkùn ati ìbànújẹ́, ọjọ́ ìkùukùu ati òkùnkùn biribiri. Ọjọ́ ipè ogun ati ariwo ogun sí àwọn ìlú olódi ati àwọn ilé-ìṣọ́ gíga. N óo mú hílàhílo bá ọmọ eniyan, kí wọ́n baà lè rìn bí afọ́jú. Nítorí pé wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA. Ẹ̀jẹ̀ wọn yóo ṣàn dànù bí omi, a óo sì sọ ẹran ara wọn nù bí ìgbẹ́. Fadaka ati wúrà wọn kò ní lè gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́jọ́ ibinu OLUWA, gbogbo ayé ni yóo jó àjórun ninu iná owú rẹ̀; nítorí pé yóo mú òpin dé bá gbogbo àwọn tí wọn ń gbé orílẹ̀ ayé. Ẹ kó ara yín jọ, kí ẹ gbìmọ̀ pọ̀, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè tí kò ní ìtìjú. Kí á tó fẹ yín dànù, bí ìgbà tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ ìyàngbò káàkiri, kí ibinu Ọlọrun tó wá sórí yín, kí ọjọ́ ìrúnú OLUWA tó dé ba yín. Ẹ wá OLUWA, gbogbo ẹ̀yin onírẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ náà, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́; ẹ jẹ́ olódodo, ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, bóyá OLUWA a jẹ́ pa yín mọ́ ní ọjọ́ ibinu rẹ̀. Àwọn eniyan yóo sá kúrò ní ìlú Gasa; ìlú Aṣikeloni yóo dahoro; a óo lé àwọn ará ìlú Aṣidodu jáde lọ́sàn-án gangan, a óo sì tú ìlú Ekironi ká. Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé etí òkun, orílẹ̀-èdè Kereti! Ọ̀rọ̀ OLUWA ń ba yín wí, Kenaani, ilẹ̀ àwọn ará Filistia; n óo pa yín run patapata láìku ẹnìkan. Ilẹ̀ etí òkun yóo di pápá oko fún àwọn darandaran, ati ibi tí àwọn ẹran ọ̀sìn yóo ti máa jẹko. Etí òkun yóo sì di ilẹ̀-ìní fún àwọn ọmọ Juda tí ó kù, níbi tí àwọn ẹran wọn yóo ti máa jẹko, ní alẹ́, wọn yóo sùn sinu àwọn ilé ninu ìlú Aṣikeloni, nítorí OLUWA Ọlọrun wọn yóo wà pẹlu wọn, yóo sì dá ohun ìní wọn pada. OLUWA ní: “Mo ti gbọ́ ọ̀rọ̀ àbùkù tí àwọn ará Moabu ń sọ ati bí àwọn ará Amoni tí ń fọ́nnu, bí wọn tí ń fi àwọn eniyan mi ṣe yẹ̀yẹ́, tí wọ́n sì ń lérí pé àwọn yóo gba ilẹ̀ wọn. Nítorí náà bí èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli, ti wà láàyè, mo búra pé, a óo pa ilẹ̀ Moabu run bí ìlú Sodomu, a óo sì run ilẹ̀ Amoni bí ìlú Gomora, yóo di oko tí ó kún fún igbó ati ihò tí wọ́n ti ń wa iyọ̀, yóo di aṣálẹ̀ títí lae, àwọn eniyan mi tí ó kù yóo kó àwọn ohun ìní wọn tí ó kù.” Wọn yóo sì gba ilẹ̀ wọn, ohun tí yóo dé bá wọn nìyí nítorí ìgbéraga wọn, nítorí pé wọ́n ń fi àwọn eniyan èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ṣe yẹ̀yẹ́. Wọ́n ń fi wọ́n fọ́nnu. OLUWA óo dẹ́rùbà wọ́n, yóo sọ gbogbo oriṣa ilé ayé di òfo, olukuluku eniyan yóo sì máa sin OLUWA ní ààyè rẹ̀ ní gbogbo orílẹ̀-èdè. Ẹ̀yin ará Etiopia, n óo fi idà mi pa yín. Èmi OLUWA yóo dojú ìjà kọ ìhà àríwá, n óo pa ilẹ̀ Asiria run; n óo sọ ìlú Ninefe di ahoro, ilẹ̀ ibẹ̀ yóo sì gbẹ bí aṣálẹ̀. Àwọn agbo ẹran yóo dùbúlẹ̀ láàrin rẹ̀, ati àwọn ẹranko ìgbẹ́, àwọn ẹyẹ igún ati òòrẹ̀ yóo sì máa gbé inú olú-ìlú rẹ̀. Ẹyẹ òwìwí yóo máa dún lójú fèrèsé, ẹyẹ ìwò yóo máa ké ní ibi ìpakà wọn tí yóo dahoro; igi kedari rẹ̀ yóo sì ṣòfò. Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún ìlú tí ó jókòó láìléwu, tí ń fọ́nnu wí pé, “Kò sí ẹlòmíràn mọ́, àfi èmi nìkan.” Wá wò ó, ó ti dahoro, ó ti di ibùgbé fún àwọn ẹranko burúkú! Gbogbo àwọn tí wọn ń gba ibẹ̀ kọjá ń pòṣé, wọ́n sì ń mi orí wọn. Ìwọ ìlú ọlọ̀tẹ̀, o gbé! Ìlú oníbàjẹ́ ati aninilára. Ìlú tí kò gba ìmọ̀ràn ati ìbáwí, tí kò gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, tí kò sì súnmọ́ Ọlọrun rẹ̀. Àwọn olóyè rẹ̀ ní ìwọ̀ra bíi kinniun tí ń bú ramúramù; àwọn onídàájọ́ rẹ̀ dàbí ìkookò tí ń jẹ ní aṣálẹ̀ tí kì í jẹ ẹran tí ó bá pa lájẹṣẹ́kù di ọjọ́ keji. Oníwọ̀ra ati alaiṣootọ eniyan ni àwọn wolii rẹ̀, àwọn alufaa rẹ̀ sì ti sọ ohun mímọ́ di aláìmọ́, wọ́n yí òfin Ọlọrun po fún anfaani ara wọn. Ṣugbọn OLUWA tí ó wà láàrin ìlú Jerusalẹmu jẹ́ olódodo, kì í ṣe ibi, kìí kùnà láti fi ìdájọ́ òdodo rẹ̀ hàn sí àwọn eniyan rẹ̀ lojoojumọ. OLUWA wí pé: “Mo ti pa àwọn orílẹ̀-èdè run; ilé-ìṣọ́ wọn sì ti di àlàpà; mo ti ba àwọn ìgboro wọn jẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè rìn níbẹ̀; àwọn ìlú wọn ti di ahoro, láìsí olùgbé kankan níbẹ̀. Mo ní, ‘Dájúdájú, wọn óo bẹ̀rù mi, wọn óo gba ìbáwí, wọn óo sì fọkàn sí gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún wọn.’ Ṣugbọn, ń ṣe ni wọ́n ń múra kankan, tí wọn ń ṣe iṣẹ́ ibi.” Nítorí náà, OLUWA ní, “Ẹ dúró dè mí di ọjọ́ tí n óo dìde bí ẹlẹ́rìí. Mo ti pinnu láti kó àwọn orílẹ̀-èdè ati àwọn ìjọba jọ, láti jẹ́ kí wọn rí ibinu mi, àní ibinu gbígbóná mi; gbogbo ayé ni yóo sì parun nítorí ìrúnú gbígbóná mi. “N óo wá yí ọ̀rọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè pada nígbà náà, yóo sì di mímọ́, kí gbogbo wọn lè máa pe orúkọ èmi OLUWA, kí wọ́n sì sìn mí pẹlu ọkàn kan. Láti ọ̀nà jíjìn, níkọjá àwọn odò Etiopia, àwọn ọmọbinrin àwọn eniyan mi tí a fọ́n káàkiri yóo mú ọrẹ ẹbọ wá fún mi. “Ní ọjọ́ náà, a kò ní dójútì yín nítorí ohun tí ẹ ṣe, tí ẹ dìtẹ̀ mọ́ mi; nítorí pé n óo yọ àwọn onigbeeraga kúrò láàrin yín, ẹ kò sì ní ṣoríkunkun sí mi mọ́ ní òkè mímọ́ mi. Nítorí pé, n óo fi àwọn onírẹ̀lẹ̀ ati aláìlera sílẹ̀ sí ààrin yín, orúkọ èmi OLUWA ni wọn yóo gbẹ́kẹ̀lé. Àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ní Israẹli kò ní hùwà burúkú mọ́, wọn kò ní purọ́ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì ní bá ẹ̀tàn lẹ́nu wọn mọ́. Wọn yóo jẹ àjẹyó, wọn yóo dùbúlẹ̀, kò sì ní sí ẹni tí yóo dẹ́rùbà wọ́n.” Ẹ kọrin sókè, kí ẹ sì hó; ẹ̀yin ọmọ Israẹli! Ẹ máa yọ̀ kí inú yín sì dùn gidigidi, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu! OLUWA ti mú ẹ̀bi yín kúrò, ó sì ti lé àwọn ọ̀tá yín lọ. OLUWA, ọba Israẹli wà lọ́dọ̀ yín; ẹ kò sì ní bẹ̀rù ibi mọ́. Ní ọjọ́ náà, a óo sọ fún Jerusalẹmu pé: “Ẹ má ṣe fòyà; ẹ má sì ṣe jẹ́ kí agbára yín dínkù. OLUWA Ọlọrun yín wà lọ́dọ̀ yín, akọni tí ń fúnni ní ìṣẹ́gun ni; yóo láyọ̀ nítorí yín, yóo tún yín ṣe nítorí ìfẹ́ rẹ̀ si yín, yóo yọ̀, yóo sì kọrin ayọ̀ sókè gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àjọ̀dún.” OLUWA ní: “N óo mú ibi kúrò lórí yín, kí ojú má baà tì yín. N óo wá kọlu àwọn ọ̀tá yín, n óo gba àwọn arọ là, n óo sì kó àwọn tí a ti fọ́nká jọ. N óo yí ìtìjú wọn pada sí ògo gbogbo aráyé ni yóo máa bu ọlá fún wọn. N óo wá mu yín pada wálé nígbà náà, nígbà tí mo bá ko yín jọ tán: n óo sọ yín di eniyan pataki ati ẹni iyì láàrin gbogbo ayé, nígbà tí mo bá dá ire yín pada lójú yín, Èmi OLUWA ni mo wí bẹ́ẹ̀.” Ní ọjọ́ kinni, oṣù kẹfa, ọdún keji ìjọba Dariusi, OLUWA rán wolii Hagai sí Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, gomina ilẹ̀ Juda, ati sí Joṣua ọmọ Jehosadaki, olórí alufaa. OLUWA àwọn ọmọ ogun ní: “Àwọn eniyan wọnyi ní, kò tíì tó àkókò láti tún Tẹmpili kọ́.” Nítorí náà ni OLUWA ṣe rán wolii Hagai sí wọn ó ní, “Ẹ̀yin eniyan mi, ṣé àkókò nìyí láti máa gbé inú ilé tiyín tí ẹ ṣe lọ́ṣọ̀ọ́, nígbà tí Tẹmpili wà ní àlàpà? Nítorí náà, nisinsinyii, ẹ kíyèsí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ si yín: Ohun ọ̀gbìn pupọ ni ẹ gbìn, ṣugbọn díẹ̀ ni ẹ kórè; ẹ jẹun, ṣugbọn ẹ kò yó; ẹ mu, ṣugbọn kò tẹ yín lọ́rùn; ẹ wọṣọ, sibẹ òtútù tún ń mu yín. Àwọn tí wọn ń gba owó iṣẹ́ wọn, inú ajádìí-àpò ni wọ́n ń gbà á sí. Ẹ kíyèsí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ si yín. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Ẹ lọ sórí àwọn òkè, kí ẹ gé igi ìrólé láti kọ́ ilé náà, kí inú mi lè dùn sí i, kí n sì lè farahàn ninu ògo mi. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA wí. “Ẹ̀ ń retí ọ̀pọ̀ ìkórè, ṣugbọn díẹ̀ ni ẹ̀ ń rí; nígbà tí ẹ sì mú díẹ̀ náà wálé, èmi á gbọ̀n ọ́n dànù. Mò ń bi yín, ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí ó fà á? Ìdí rẹ̀ ni pé, ẹ fi ilé mi sílẹ̀ ní òkítì àlàpà, olukuluku sì múra sí kíkọ́ ilé tirẹ̀. Ìdí nìyí tí ìrì kò fi sẹ̀ láti òkè ọ̀run wá, tí ilẹ̀ kò sì fi so èso bí ó ti yẹ. Mo mú ọ̀gbẹlẹ̀ wá sórí ilẹ̀, ati sórí àwọn òkè, ati oko ọkà, ati ọgbà àjàrà ati ọgbà igi olifi. Bẹ́ẹ̀ náà ló kan gbogbo ohun tí ń hù lórí ilẹ̀, ati eniyan ati ẹran ọ̀sìn, ati gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ eniyan.” Ni Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli ati Joṣua ọmọ Jehosadaki, olórí alufaa, ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n ṣẹ́kù bá gbọ́ràn sí OLUWA Ọlọrun wọn lẹ́nu, wọ́n fetí sí ọ̀rọ̀ wolii Hagai, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun wọn ti rán an; wọ́n sì bẹ̀rù OLUWA. Ni Hagai, òjíṣẹ́ OLUWA, bá jẹ́ iṣẹ́ tí OLUWA rán an sí àwọn eniyan náà pé òun OLUWA ní òun wà pẹlu wọn. OLUWA bá fi ìtara rẹ̀ sí ọkàn Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, gomina ilẹ̀ Juda, ati sí ọkàn Joṣua ọmọ Jehosadaki, olórí alufaa ati ọkàn gbogbo àwọn tí wọ́n pada dé láti oko ẹrú. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun wọn. Ọjọ́ kẹrinlelogun, oṣù kẹfa, ọdún keji ìjọba Dariusi, ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé náà. Ní ọjọ́ kọkanlelogun oṣù keje, ọdún keji ìjọba Dariusi, OLUWA tún sọ fún wolii Hagai, pé: “Tún lọ sọ́dọ̀ Serubabeli ọmọ Ṣealitieli, gomina ilẹ̀ Juda, ati Joṣua ọmọ Jehosadaki, olórí alufaa ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n ṣẹ́kù, kí o bèèrè pé, ‘Àwọn wo ni wọ́n ṣẹ́kù ninu yín tí wọ́n rí i bí ẹwà ògo ilé yìí ti pọ̀ tó tẹ́lẹ̀? Báwo ni ẹ ti rí i sí nisinsinyii? Ǹjẹ́ ó jẹ́ nǹkankan lójú yín? Ṣugbọn, mú ọkàn le, ìwọ Serubabeli, má sì fòyà, ìwọ Joṣua, ọmọ Jehosadaki, olórí alufaa; ẹ ṣe ara gírí kí ẹ sì ṣe iṣẹ́ náà ẹ̀yin eniyan; nítorí mo wà pẹlu yín. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA wí. Gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí mo ṣe fun yín, nígbà tí ẹ jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, mo wà láàrin yín; nítorí náà, ẹ má ṣe bẹ̀rù.’ “Nítorí pé èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ ọ́ pé láìpẹ́, n óo tún mi ọ̀run ati ayé jìgìjìgì lẹ́ẹ̀kan sí i, ati òkun ati ilẹ̀. N óo mi gbogbo orílẹ̀-èdè, wọn óo kó ìṣúra wọn wá, n óo sì ṣe ilé yìí lọ́ṣọ̀ọ́. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí. Tèmi ni gbogbo fadaka ati wúrà tí ó wà láyé; èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Ògo tí ilé yìí yóo ní tó bá yá, yóo ju ti àtijọ́ lọ. N óo fún àwọn eniyan mi ní alaafia ati ibukun ninu rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí.” Ní ọjọ́ kẹrinlelogun oṣù kẹsan-an, ní ọdún keji ìjọba Dariusi, OLUWA sọ fún wolii Hagai pé, “Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo ní kí o lọ bèèrè ìdáhùn lórí ọ̀rọ̀ yìí lọ́wọ́ àwọn alufaa. Ǹjẹ́ bí ẹnìkan bá mú ẹran tí a fi rúbọ, tí ó ti di mímọ́, tí ó dì í mọ́ ìṣẹ́tí ẹ̀wù rẹ̀, tí ó sì fi ẹ̀wù náà kan burẹdi, tabi àsáró, tabi waini, tabi òróró, tabi oúnjẹ-kóúnjẹ, ṣé ọ̀kan kan ninu àwọn oúnjẹ yìí lè tipa bẹ́ẹ̀ di mímọ́?” Àwọn alufaa bá dáhùn pé, “Rárá.” Nígbà náà ni Hagai tún bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ bí ẹnìkan bá di aláìmọ́ nítorí pé ó farakan òkú, tí ó sì fọwọ́ kan ọ̀kan ninu àwọn ohun tí a kà sílẹ̀ wọnyi ǹjẹ́ kò ní di aláìmọ́?” Wọ́n dáhùn pé: “Dájúdájú, yóo di aláìmọ́.” Hagai bá dáhùn, ó ní: “Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí fún àwọn eniyan wọnyi ati fún orílẹ̀-èdè yìí pẹlu iṣẹ́ ọwọ́ wọn níwájú OLUWA; gbogbo ohun tí wọ́n fi ń rúbọ jẹ́ aláìmọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA wí. OLUWA ní, “Nisinsinyii, ẹ kíyèsí ohun tí yóo máa ṣẹlẹ̀ láti àkókò yìí lọ. Ẹ ranti bí ó ti rí fun yín kí ẹ tó fi ìpìlẹ̀ tẹmpili yìí lélẹ̀. Ninu oko tí ẹ tí ń retí pé ẹ óo rí ogún òṣùnwọ̀n ọkà, mẹ́wàá péré ni ẹ rí; níbi tí ẹ tí ń retí pé ẹ óo rí aadọta ìgò ọtí, ogún péré ni ẹ rí níbẹ̀. Mo kọlù yín, mo sì mú kí atẹ́gùn gbígbóná ati yìnyín wó ohun ọ̀gbìn yín lulẹ̀, sibẹsibẹ ẹ kò ronupiwada, kí ẹ pada sọ́dọ̀ mi. Lónìí ọjọ́ kẹrinlelogun oṣù kẹsan-an, ni ẹ fi ìpìlẹ̀ tẹmpili lélẹ̀; láti òní lọ, ẹ kíyèsí ohun tí yóo máa ṣẹlẹ̀. Kò sí ọkà ninu abà mọ, igi àjàrà ati igi ọ̀pọ̀tọ́ kò sì tíì so; bẹ́ẹ̀ ni igi pomegiranate, ati igi olifi. Ṣugbọn láti òní lọ, n óo bukun yín.” Ní ọjọ́ kan náà, tíí ṣe ọjọ́ kẹrinlelogun oṣù kẹsan-an, OLUWA tún rán Hagai, pé kí ó sọ fún Serubabeli, gomina ilẹ̀ Juda pé òun OLUWA ní, “N óo mi ọ̀run ati ayé jìgìjìgì. N óo lé àwọn ìjọba kúrò ní ipò wọn; n óo sì ṣẹ́ àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè lápá. N óo ta kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn tí wọn ń gùn wọ́n lókìtì. Ẹṣin ati àwọn tí wọn ń gùn wọ́n yóo ṣubú, wọn óo sì fi idà pa ara wọn. Ní ọjọ́ náà, n óo fi ìwọ Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, ṣe aṣojú ninu ìjọba mi nítorí pé mo ti yàn ọ́. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí.” Ní oṣù kẹjọ, ọdún keji ìjọba Dariusi, OLUWA rán wolii Sakaraya, ọmọ Berekaya, ọmọ Ido, sí àwọn ọmọ Israẹli; ó ní, “Èmi OLUWA bínú sí àwọn baba ńlá yín. Nítorí náà, èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ní kí ẹ pada wá sọ́dọ̀ mi, èmi náà yóo sì pada sọ́dọ̀ yín. Ẹ má ṣe bí àwọn baba ńlá yín, tí àwọn wolii mi rọ̀ títí pé kí wọ́n jáwọ́ ninu ìgbé-ayé burúkú, kí wọ́n jáwọ́ ninu iṣẹ́ ibi, ṣugbọn tí wọ́n kọ̀, tí wọn kò gbọ́. Níbo ni àwọn baba ńlá yín ati àwọn wolii wà nisinsinyii? Ǹjẹ́ wọ́n wà mọ́? Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ mi ati ìlànà mi tí àwọn wolii, iranṣẹ mi, sọ kò ṣẹ sí àwọn baba ńlá yín lára?” Àwọn eniyan náà bá ronupiwada, wọ́n ní, “OLUWA àwọn ọmọ ogun ti ṣe wá bí ó ti pinnu láti ṣe, nítorí ìwà burúkú ati iṣẹ́ ibi wa.” Ní ọjọ́ kẹrinlelogun oṣù kọkanla tíí ṣe oṣù Ṣebati, ní ọdún keji ìjọba Dariusi, OLUWA fi ìran kan han wolii Sakaraya ọmọ Berekaya, ọmọ Ido. Mo rí ìran kan lóru. Ninu ìran náà, mo rí ọkunrin kan lórí ẹṣin pupa, láàrin àwọn igi kan tí wọ́n ń pè ní mitili, láàrin àfonífojì kan. Àwọn ẹṣin pupa, ati ẹṣin rẹ́súrẹ́sú ati ẹṣin funfun dúró lẹ́yìn rẹ̀. Mo bá bèèrè pé, “OLUWA mi, kí ni ìtumọ̀ kinní wọnyi?” Angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ sì dáhùn pé, “N óo sọ ìtumọ̀ wọn fún ọ.” Ọkunrin tí ó dúró láàrin àwọn igi mitili náà bá dáhùn pé, “Àwọn wọnyi ni àwọn tí OLUWA rán láti máa rin ilẹ̀ ayé wò.” Wọ́n sì jíṣẹ́ fún angẹli OLUWA, tí ó dúró láàrin àwọn igi mitili náà pé, “A ti lọ rin ilẹ̀ ayé wò jákèjádò, a sì rí i pé wọ́n wà ní alaafia ati ìdákẹ́rọ́rọ́.” Angẹli OLUWA bá dáhùn pé, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, yóo ti pẹ́ tó kí o tó yọ́nú sí Jerusalẹmu ati àwọn ìlú Juda, tí o tí ń bínú sí láti aadọrin ọdún sẹ́yìn?” OLUWA sì dá angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ lóhùn pẹlu ọ̀rọ̀ ìtùnú. Angẹli náà bá sọ fún mi pé kí n lọ kéde pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Mo ní ìfẹ́ ati ìtara tí ó jinlẹ̀ pupọ fún Jerusalẹmu ati Sioni. Inú sì ń bí mi gidigidi sí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n dákẹ́ jẹ́ẹ́ tí wọ́n sì wà ní alaafia; nítorí pé, nígbà tí mo bínú díẹ̀ sí àwọn eniyan mi, wọ́n tún dá kún ìṣòro wọn ni. Nítorí náà, mo ti pada sí Jerusalẹmu láti ṣàánú fún un: a óo tún ilé mi kọ́ sibẹ, a óo sì tún ìlú Jerusalẹmu kọ́.” Angẹli náà tún sọ fún mi pé, “Lọ kéde pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, àwọn ìlú òun yóo tún kún fún ọrọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, òun OLUWA yóo tu Sioni ninu, òun óo sì tún yan Jerusalẹmu ní àyànfẹ́ òun.” Bí mo ti gbé ojú sókè ni mo rí ìwo mààlúù mẹrin, mo sì bèèrè ìtumọ̀ ohun tí mo rí lọ́wọ́ angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀. Ó bá dá mi lóhùn pé, “Àwọn ìwo wọnyi dúró fún àwọn alágbára ayé tí wọ́n fọ́n Juda, Israẹli, ati Jerusalẹmu ká.” Lẹ́yìn náà, OLUWA fi àwọn alágbẹ̀dẹ mẹrin kan hàn mí. Mo bèèrè pé, “Kí ni àwọn wọnyi ń bọ̀ wá ṣe?” Ó bá dáhùn pé, “Àwọn ìwo wọnyi dúró fún àwọn tí wọ́n fọ́n Juda ká patapata, tóbẹ́ẹ̀ tí kò ku ẹnìkan mọ́. Ṣugbọn àwọn alágbẹ̀dẹ wọnyi wá láti dẹ́rùba àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n fọ́n Juda ká, ati láti fọ́n àwọn náà ká.” Bí mo tún ti gbé ojú sókè, mo rí ọkunrin kan tí ó mú okùn ìwọ̀n lọ́wọ́. Mo bi í pé, “Níbo ni ò ń lọ?” Ó bá dáhùn pé, “Mò ń lọ wọn Jerusalẹmu, kí n lè mọ òòró ati ìbú rẹ̀ ni.” Angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ bá bọ́ siwaju, angẹli mìíràn sì lọ pàdé rẹ̀, Angẹli àkọ́kọ́ sọ fún ekeji pé, “Sáré lọ sọ fún ọmọkunrin tí ó ní okùn ìwọ̀n lọ́wọ́ pé, eniyan ati ẹran ọ̀sìn yóo pọ̀ ní Jerusalẹmu tóbẹ́ẹ̀ tí a kò ní lè mọ odi yí i ká. Èmi fúnra mi ni n óo jẹ́ odi iná tí n óo yí i ká, tí n óo máa dáàbò bò ó, n óo sì fi ògo mi kún inú rẹ̀.” OLUWA sọ fún àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ẹ sá àsálà kúrò ní ilẹ̀ àríwá. Lóòótọ́ èmi ni mo fọn yín ká bí afẹ́fẹ́ sí igun mẹrẹẹrin ayé, ṣugbọn nisinsinyii, ẹ sá àsálà lọ sí Sioni, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Babiloni. Nítorí èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó rán ni sí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ko yín lẹ́rú, nítorí ẹni tí ó bá fọwọ́ kàn yín, fọwọ́ kan ẹyinjú èmi OLUWA.” N óo bá àwọn ọ̀tá yín jà; wọn yóo sì di ẹrú àwọn tí ń sìn wọ́n. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA àwọn ọmọ ogun. OLUWA ní, “Ẹ kọrin ayọ̀, kí ẹ sì jẹ́ kí inú yín máa dùn, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, nítorí pé mò ń bọ̀ wá máa ba yín gbé. Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ni yóo parapọ̀ láti di eniyan mi nígbà náà. N óo máa gbé ààrin yín; ẹ óo sì mọ̀ pé èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo ranṣẹ si yín. N óo jogún Juda bí ohun ìní mi ninu ilẹ̀ mímọ́, n óo sì yan Jerusalẹmu.” Ẹ̀yin eniyan, ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú OLUWA, nítorí ó ń jáde bọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, OLUWA fi Joṣua olórí alufaa hàn mí; ó dúró níwájú angẹli OLUWA, Satani sì dúró lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ láti fi ẹ̀sùn kàn án. Angẹli OLUWA sọ fún Satani pé, “OLUWA óo bá ọ wí, ìwọ Satani! OLUWA tí ó yan Jerusalẹmu óo bá ọ wí! Ṣebí ẹ̀ka igi tí a yọ jáde láti inú iná ni ọkunrin yìí?” Joṣua dúró níwájú angẹli Ọlọrun, pẹlu aṣọ tí ó dọ̀tí ní ọrùn rẹ̀. Angẹli náà bá sọ fún àwọn tí wọ́n dúró tì í pé, “Ẹ bọ́ aṣọ tí ó dọ̀tí yìí kúrò lọ́rùn rẹ̀.” Ó bá sọ fún Joṣua pé, “Wò ó! Mo ti mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò, n óo sì fi aṣọ tí ó lẹ́wà wọ̀ ọ́.” Ó bá pàṣẹ pé, “Ẹ fi aṣọ mímọ́ wé e lórí.” Wọ́n bá fi aṣọ mímọ́ wé e lórí, wọ́n wọ̀ ọ́ ní aṣọ funfun, angẹli OLUWA sì dúró tì í. Angẹli náà kìlọ̀ fún Joṣua pé, OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Bí o bá tẹ̀lé ọ̀nà mi, tí o sì pa òfin mi mọ́, o óo di alákòóso ilé mi ati àwọn àgbàlá rẹ̀. N óo sì fún ọ ní ipò láàrin àwọn tí wọ́n dúró wọnyi. Gbọ́ nisinsinyii, ìwọ Joṣua, olórí alufaa, ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin alufaa alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀, ẹ̀yin ni àmì ohun rere tí ń bọ̀, pé n óo mú iranṣẹ mi wá, tí a pè ní Ẹ̀ka. Wò ó! Nítorí mo gbé òkúta kan tí ó ní ojú meje siwaju Joṣua, n óo sì kọ àkọlé kan sórí rẹ̀. Lọ́jọ́ kan ṣoṣo ni n óo mú ẹ̀ṣẹ̀ ilẹ̀ yìí kúrò. Ní ọjọ́ náà, olukuluku yóo pe aládùúgbò rẹ̀ láti wá bá a ṣe fàájì lábẹ́ àjàrà ati igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀.” Angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ tún pada wá, ó jí mi bí ẹni pé mo sùn. Ó bi mí pé kí ni mo rí. Mo dáhùn pé, “Mo rí ọ̀pá fìtílà wúrà, àwo kan sì wà lórí rẹ̀. Fìtílà meje wà lórí ọ̀pá náà, fìtílà kọ̀ọ̀kan sì ní òwú fìtílà meje. Igi olifi meji wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ fìtílà náà, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àwo náà, ọ̀kan ní apá òsì.” Nígbà náà ni mo bi angẹli náà pé, “OLUWA mi, Kí ni ìtumọ̀ àwọn kinní wọnyi?” Ó bá bèèrè lọ́wọ́ mi pé, “Ṣé o kò mọ ìtumọ̀ wọn ni?” Mo dáhùn pé, “Rárá, oluwa mi, n kò mọ̀ ọ́n.” Angẹli náà sọ fún mi pé, “Iṣẹ́ tí OLUWA àwọn ọmọ ogun rán sí Serubabeli ni pé, ‘Kì í ṣe nípa ipá, kì í ṣe nípa agbára, bíkòṣe nípa ẹ̀mí mi. Kí ni òkè ńlá jámọ́ níwájú Serubabeli? Yóo di pẹ̀tẹ́lẹ̀. Serubabeli, O óo kọ́ ilé náà parí, bí o bá sì ti ń parí rẹ̀ ni àwọn eniyan yóo máa kígbe pé, “Áà! Èyí dára! Ó dára!” ’ ” OLUWA tún rán mi pé, “Serubabeli tí ó bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ilé Ọlọrun yìí ni yóo parí rẹ̀. Nígbà náà ni àwọn eniyan mi yóo mọ̀ pé èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo rán ọ sí wọn. Inú àwọn tí wọn ń pẹ̀gàn ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ yìí yóo dùn, wọn yóo sì rí okùn ìwọ̀n lọ́wọ́ Serubabeli. Àwọn fìtílà meje wọnyi ni ojú OLUWA tí ń wo gbogbo ayé.” Mo bá bi í pé, “Kí ni ìtumọ̀ àwọn igi olifi meji tí wọ́n wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ fìtílà náà?” Mo tún bèèrè lẹẹkeji pé, “Kí ni ìtumọ̀ ẹ̀ka olifi meji, tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ fèrè wúrà meji, tí òróró olifi ń ṣàn jáde ninu wọn?” Ó tún bèèrè lọ́wọ́ mi pé, “Ṣé o kò mọ ohun tí wọ́n jẹ́ ni?” Mo dáhùn pé, “Rárá, oluwa mi, n kò mọ̀ ọ́n.” Ó bá dáhùn, ó ní, “Àwọn wọnyi ni àwọn meji tí a ti fi òróró yàn láti jẹ́ òjíṣẹ́ OLUWA gbogbo ayé.” Mo tún gbé ojú sókè, mo bá rí ìwé kíká kan tí ń fò ní òfuurufú. Angẹli náà bi mí pé, “Kí ni o rí?” Mo bá dáhùn pé “Mo rí ìwé kíká kan tí ń fò ní òfuurufú. Ìwé náà gùn ní ìwọ̀n ogún igbọnwọ, (mita 9); ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹ́wàá (mita 4½).” Ó bá sọ fún mi pé, “Ègún tí yóo máa káàkiri gbogbo ilẹ̀ náà ni a kọ sinu ìwé yìí. Láti ìsinsìnyìí lọ, ẹnikẹ́ni tí ó bá jalè ati ẹnikẹ́ni tí ó bá búra èké, a óo yọ orúkọ rẹ̀ kúrò ní ilẹ̀ náà.” OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “N óo rán ègún náà lọ sí ilé àwọn olè ati sí ilé àwọn tí wọn ń búra èké ní orúkọ mi. Yóo wà níbẹ̀ títí yóo fi run ilé náà patapata, ati igi ati òkúta rẹ̀.” Angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ bá jáde, ó ní, “Gbé ojú rẹ sókè kí o tún wo kinní kan tí ń bọ̀.” Mo bèèrè pé, “Kí ni èyí?” Ó dáhùn pé, “Agbọ̀n òṣùnwọ̀n eefa kan ni. Ó dúró fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan jákèjádò ilẹ̀ yìí.” Nígbà tí wọ́n ṣí ìdérí òjé tí wọ́n fi bo agbọ̀n náà kúrò lórí rẹ̀, mo rí obinrin kan tí ó jókòó sinu eefa náà. Angẹli náà sọ pé “Ìwà ìkà ni obinrin yìí dúró fún.” Ó ti obinrin náà pada sinu agbọ̀n eefa náà, ó sì fi ìdérí òjé náà dé e mọ́ ibẹ̀ pada. Bí mo ti gbé ojú sókè ni mo rí àwọn obinrin meji tí wọn ń fi tagbára tagbára fò bọ̀, ìyẹ́ apá wọn dàbí ìyẹ́ ẹyẹ àkọ̀. Wọ́n hán agbọ̀n náà, wọ́n sì ń fò lọ. Mo bi angẹli náà pé, “Níbo ni wọ́n ń gbé e lọ?” Ó dáhùn pé, “Ilẹ̀ Ṣinari ni wọ́n ń gbé e lọ, láti lọ kọ́lé fún un níbẹ̀. Tí wọ́n bá parí ilé náà, wọn yóo gbé e kalẹ̀ sibẹ.” Mo tún gbé ojú sókè, mo rí kẹ̀kẹ́ ogun mẹrin tí ń bọ̀ láàrin òkè meji; òkè idẹ ni àwọn òkè náà. Àwọn ẹṣin pupa ni wọ́n ń fa kẹ̀kẹ́ ogun àkọ́kọ́, àwọn ẹṣin dúdú ń fa kẹ̀kẹ́ ogun keji, ẹṣin funfun ń fa ẹkẹta, àwọn tí wọn ń fa ẹkẹrin sì jẹ́ kàláńkìnní. Mo bi angẹli náà pé, “Oluwa mi, kí ni ìtumọ̀ ìwọ̀nyí?” Angẹli náà bá dáhùn pé, “Àwọn wọnyi ni wọ́n ń lọ sí igun mẹrẹẹrin ayé lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ara wọn han Ọlọrun ẹlẹ́dàá gbogbo ayé.” Àwọn ẹṣin dúdú ń fa kẹ̀kẹ́ tiwọn lọ sí ìhà àríwá, àwọn ẹṣin funfun ń lọ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn, àwọn tí wọ́n jẹ́ kàláńkìnní ń lọ sí ìhà gúsù. Bí àwọn ẹṣin tí wọ́n jẹ́ kàláńkìnní ti jáde, wọ́n ń kánjú láti lọ máa rin ayé ká. Angẹli náà bá pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n lọ; wọ́n sì lọ. Angẹli náà bá ké sí mi, ó ní, “Àwọn ẹṣin tí wọn ń lọ sí ìhà àríwá ti jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀ nípa ibẹ̀.” OLUWA pàṣẹ fún mi pé, “Lára àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ti oko ẹrú Babiloni dé, mú Helidai, Tobija ati Jedaaya lẹsẹkẹsẹ, kí o lọ sí ilé Josaya ọmọ Sefanaya. Gba fadaka ati wúrà lọ́wọ́ wọn, kí o fi ṣe adé, kí o sì fi adé náà dé Joṣua olórí alufaa, ọmọ Jehosadaki lórí. Kí o sì sọ ohun tí èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí fún un, pé, ‘Wò ó! Ọkunrin tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹ̀ka ni yóo gba ipò rẹ̀, òun ni yóo sì kọ́ ilé OLUWA. Òun gan-an ni yóo kọ́ ọ, tí yóo sì gba ògo ati ẹ̀yẹ tí ó yẹ fún ọba, yóo sì jọba lórí ìtẹ́ rẹ̀. Yóo ní alufaa gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn, wọn yóo sì máa ṣiṣẹ́ pọ̀ ní alaafia.’ Adé náà yóo wà ní ilé OLUWA gẹ́gẹ́ bí ohun ìrántí fún Helidai ati Tobija ati Jedaaya ati Josaya, ọmọ Sefanaya. “Àwọn tí wọ́n wà ní ọ̀nà jíjìn réré yóo wá láti ba yín kọ́ ilé OLUWA. Ẹ óo wá mọ̀ dájú pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó rán mi si yín. Gbogbo nǹkan wọnyi yóo ṣẹ patapata bí ẹ bá pa òfin OLUWA Ọlọrun yín mọ́.” Ní ọjọ́ kẹrin oṣù kẹsan-an, tíí ṣe oṣù Kisilefi, ní ọdún kẹrin ìjọba Dariusi, ni OLUWA rán mi níṣẹ́ yìí. Àwọn ará Bẹtẹli rán Ṣareseri ati Regemumeleki ati gbogbo àwọn eniyan wọn lọ sí ilé OLUWA; wọ́n lọ wá ojurere OLUWA, wọn sì lọ bèèrè lọ́wọ́ àwọn alufaa ilé OLUWA, àwọn ọmọ ogun ati àwọn wolii pé, “Nígbà wo ni a óo dẹ́kun láti máa ṣọ̀fọ̀, ati láti máa gbààwẹ̀ ní oṣù karun-un bí a ti ń ṣe láti ọpọlọpọ ọdún sẹ́yìn?” OLUWA àwọn ọmọ ogun bá rán mi pé, “Sọ fún gbogbo àwọn eniyan ilẹ̀ náà ati àwọn alufaa pé, nígbà tí ẹ̀ ń gbààwẹ̀, tí ẹ sì ń ṣọ̀fọ̀ ní oṣù karun-un ati oṣù keje fún odidi aadọrin ọdún, ṣé èmi ni ẹ̀ ń gbààwẹ̀ fún? Tabi nígbà tí ẹ̀ ń jẹ tí ẹ sì ń mu, kì í ṣe ara yín ni ẹ̀ ń jẹ tí ẹ̀ ń mu fún?” Nígbà tí nǹkan fi ń dára fún Jerusalẹmu, tí eniyan sì pọ̀ níbẹ̀, ati àwọn ìlú agbègbè tí ó yí i ká, ati àwọn ìlú ìhà gúsù ati ti ẹsẹ̀ òkè ní ìwọ̀ oòrùn; ṣebí àwọn wolii OLUWA ti sọ nǹkan wọnyi tẹ́lẹ̀? OLUWA tún rán Sakaraya kí ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gbọdọ̀ máa dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́, kí ẹ sì fi àánú ati ìyọ́nú hàn sí ara yín. Ẹ má máa fi ìyà jẹ àwọn opó, tabi àwọn aláìníbaba, tabi àwọn àlejò tí wọn ń gbé ààrin yín, tabi àwọn aláìní. Ẹ má máa gbèrò ibi sí ẹnikẹ́ni.” Ṣugbọn àwọn eniyan kò gbọ́, wọ́n ṣe oríkunkun, wọ́n kọ̀ wọn kò gbọ́ tèmi. Wọ́n ṣe agídí, wọ́n kọ̀ wọn kò gbọ́ òfin ati ọ̀rọ̀ tí OLUWA àwọn ọmọ ogun fi agbára ẹ̀mí rẹ̀ rán sí wọn, láti ẹnu àwọn wolii. Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun bínú sí wọn gidigidi. “Nígbà tí mo pè wọ́n, wọn kò gbọ́, nítorí náà ni n kò fi ní fetí sí wọn nígbà tí wọ́n bá ké pè mí. Bí ìjì líle tí ń fọ́n nǹkan káàkiri bẹ́ẹ̀ ni mo fọ́n wọn ká sáàrin àwọn orílẹ̀-èdè àjèjì. Ilẹ̀ dáradára tí wọ́n fi sílẹ̀ di ahoro, tóbẹ́ẹ̀ tí kò sí ẹnikẹ́ni níbẹ̀ mọ́.” OLUWA àwọn ọmọ ogun tún bá mi sọ̀rọ̀ pé Òun fẹ́ràn àwọn ará Sioni; nítorí náà ni inú òun ṣe ru sí àwọn ọ̀tá wọn. Ó ní, òun óo pada sí Sioni, òun óo máa gbé Jerusalẹmu, a óo máa pe Jerusalẹmu ní ìlú olóòótọ́, òkè OLUWA àwọn ọmọ ogun, ati òkè mímọ́. Àwọn arúgbó lọkunrin, lobinrin, tí wọn ń tẹ̀pá yóo jókòó ní ìgboro Jerusalẹmu, ìta ati òpópónà yóo sì kún fún àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin tí wọn ń ṣeré. OLUWA àwọn ọmọ ogun ní bí eléyìí bá jẹ́ ohun ìyanu lójú àwọn eniyan yòókù, ǹjẹ́ ó yẹ kí ó jẹ́ ohun ìyanu lójú òun náà? Ó ní òun óo gba àwọn eniyan òun là láti orílẹ̀-èdè tí ó wà ní ìlà oòrùn ati ti ìwọ̀ rẹ̀, òun óo mú wọn pada wá sí Jerusalẹmu láti máa gbébẹ̀; wọn óo jẹ́ eniyan òun, òun náà óo sì jẹ́ Ọlọrun wọn, lóòótọ́ ati lódodo. OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Ẹ ṣara gírí, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbọ́ ọ̀rọ̀ tí àwọn wolii tí ń sọ láti ìgbà tí a ti fi ìpìlẹ̀ ilé OLUWA àwọn ọmọ ogun lélẹ̀, kí ẹ baà lè kọ́ ilé náà parí. Nítorí ṣáájú àkókò náà, kò sí owó iṣẹ́ fún eniyan tabi ẹranko, eniyan kò sì lè rin ìrìn àjò láìléwu; nítorí àwọn ọ̀tá tí wọ́n wà káàkiri, nítorí mo mú kí olukuluku lòdì sí ẹnìkejì rẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, n kò ní ṣe sí àwọn eniyan yòókù yìí bí mo ti ṣe sí àwọn ti iṣaaju. Alaafia ni wọn yóo fi gbin èso wọn, àjàrà wọn yóo so jìnwìnnì, òjò yóo rọ̀, ilẹ̀ yóo sì mú èso jáde. Àwọn eniyan mi tí ó ṣẹ́kù ni yóo sì ni gbogbo nǹkan wọnyi. Ẹ̀yin ilé Juda ati ilé Israẹli, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé orúkọ yín ni àwọn eniyan fi ń ṣépè lé àwọn mìíràn tẹ́lẹ̀, ṣugbọn nisinsinyii, n óo gbà yín, ẹ óo sì di orísun ibukun. Nítorí náà, ẹ mọ́kànle, ẹ má bẹ̀rù.” OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Gẹ́gẹ́ bí mo ti pinnu láti ṣe yín ní ibi nígbà tí àwọn baba yín mú mi bínú, tí n kò sì yí ìpinnu mi pada, bẹ́ẹ̀ ni mo tún pinnu nisinsinyii láti ṣe ẹ̀yin ará Jerusalẹmu ati àwọn ará ilé Juda ní rere. Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù. Àwọn nǹkan tí ó yẹ kí ẹ máa ṣe nìyí: ẹ máa bá ara yín sọ òtítọ́, kí ẹ sì máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́ nílé ẹjọ́; èyí ni yóo máa mú alaafia wá. Ẹ má máa gbèrò ibi sí ara yín, ẹ má sì fẹ́ràn ìbúra èké, nítorí gbogbo nǹkan wọnyi ni mo kórìíra.” OLUWA àwọn ọmọ ogun tún bá Sakaraya sọ̀rọ̀, ó ní, “Ààwẹ̀ tí ẹ̀ ń gbà ní oṣù kẹrin, oṣù karun-un, oṣù keje, ati oṣù kẹwaa yóo di àkókò ayọ̀ ati inú dídùn ati àkókò àríyá fun yín. Nítorí náà, ẹ fẹ́ òtítọ́ ati alaafia. “Ọ̀pọ̀ eniyan yóo ti oríṣìíríṣìí ìlú wá sí Jerusalẹmu, àwọn ará ìlú kan yóo máa rọ àwọn ará ìlú mìíràn pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ kíákíá láti wá ojurere OLUWA, ati láti sin OLUWA àwọn ọmọ ogun; ibẹ̀ ni mò ń lọ báyìí.’ Ọpọlọpọ eniyan ati àwọn orílẹ̀-èdè ńlá yóo wá sin OLUWA àwọn ọmọ ogun, wọn óo sì wá wá ojurere rẹ̀ ní Jerusalẹmu. Nígbà tó bá yá, eniyan mẹ́wàá láti oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè yóo rọ̀ mọ́ aṣọ Juu kanṣoṣo, wọn yóo sì wí fún un pé, ‘Jẹ́ kí á máa bá ọ lọ, nítorí a gbọ́ pé Ọlọrun wà pẹlu yín.’ ” OLUWA ní ilẹ̀ Hadiraki yóo jìyà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìlú Damasku. Nítorí pé OLUWA ló ni àwọn ìlú Aramu, bí ó ti ni àwọn ẹ̀yà Israẹli. Tirẹ̀ ni ilẹ̀ Hamati tí ó bá Israẹli pààlà. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn ìlú Tire ati Sidoni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Ìlú Tire ti mọ odi ààbò yí ara rẹ̀ ká, ó ti kó fadaka jọ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, ó sì rọ́ wúrà jọ bíi pàǹtí láàrin ìta gbangba. Ṣugbọn OLUWA yóo gba gbogbo ohun ìní Tire, yóo kó gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ dà sinu òkun, iná yóo sì jó o ní àjórun. Ìlú Aṣikeloni yóo rí i, ẹ̀rù yóo sì bà á, ìlú Gasa yóo rí i, yóo sì máa joró nítorí ìrora. Bákan náà ni yóo rí fún ìlú Ekironi, nítorí ìrètí rẹ̀ yóo di òfo. Ọba ìlú Gasa yóo ṣègbé, ìlú Aṣikeloni yóo sì di ahoro. Oríṣìíríṣìí ẹ̀yà ni yóo máa gbé Aṣidodu; ìgbéraga Filistia yóo sì dópin. N óo gba ẹ̀jẹ̀ ati ohun ìríra kúrò ní ẹnu rẹ̀, àwọn tí yóo kù ninu wọn yóo di ti Ọlọrun wa; wọn yóo dàbí ìdílé kan ninu ẹ̀yà Juda, ìlú Ekironi yóo sì dàbí ìlú Jebusi. Ṣugbọn n óo dáàbò bo ilé mi, kí ogun ọ̀tá má baà kọjá níbẹ̀; aninilára kò ní mú wọn sìn mọ́, nítorí nisinsinyii, èmi fúnra mi ti fi ojú rí ìyà tí àwọn eniyan mi ti jẹ. Ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ará Sioni! Ẹ hó ìhó ayọ̀, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu! Wò ó! Ọba yín ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín; ajagun-ṣẹ́gun ni, sibẹsibẹ ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó sì gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, kódà, ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni ó gùn. OLUWA ní, òun óo kó kẹ̀kẹ́ ogun kúrò ní Efuraimu, òun óo kó ẹṣin ogun kúrò ní Jerusalẹmu, a óo sì ṣẹ́ ọfà ogun. Yóo fún àwọn orílẹ̀-èdè ní alaafia, ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ yóo jẹ́ láti òkun dé òkun ati láti odò Yufurate títí dé òpin ayé. Ìwọ ní tìrẹ, nítorí ẹ̀jẹ̀ tí mo fi bá ọ dá majẹmu, n óo dá àwọn eniyan rẹ tí a kó lẹ́rú sílẹ̀ láti inú kànga tí kò lómi. Ẹ pada sí ibi ààbò yín, ẹ̀yin tí a kó lẹ́rú lọ tí ẹ sì ní ìrètí; mo ṣèlérí lónìí pé, n óo dá ibukun yín pada ní ìlọ́po meji. Nítorí mo ti tẹ Juda bí ọrun mi, mo sì ti fi Efuraimu ṣe ọfà rẹ̀. Ìwọ Sioni, n óo lo àwọn ọmọ rẹ bí idà, láti pa àwọn ará Giriki run, n óo sì fi tagbára tagbára lò yín bí idà àwọn jagunjagun. OLUWA yóo fara han àwọn eniyan rẹ̀, yóo ta ọfà rẹ̀ bíi mànàmáná. OLUWA Ọlọrun yóo fọn fèrè ogun yóo sì rìn ninu ìjì líle ti ìhà gúsù. OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo dáàbò bo àwọn eniyan rẹ̀. Wọn óo borí àwọn ọ̀tá wọn, wọn óo fi idà pa àwọn ọ̀tá wọn, ẹ̀jẹ̀ wọn yóo sì máa ṣàn bíi ti ẹran ìrúbọ, tí a dà sórí pẹpẹ, láti inú àwo tí wọ́n fi ń gbe ẹ̀jẹ̀ ẹran. Ní ọjọ́ náà, OLUWA Ọlọrun wọn yóo gbà wọ́n, bí ìgbà tí olùṣọ́-aguntan bá gba àwọn aguntan rẹ̀. Wọn óo máa tàn ní ilẹ̀ rẹ̀, bí òkúta olówó iyebíye tíí tàn lára adé. Báwo ni ilẹ̀ náà yóo ti dára tó, yóo sì ti lẹ́wà tó? Ọkà yóo sọ àwọn ọdọmọkunrin di alágbára ọtí waini titun yóo sì fún àwọn ọdọmọbinrin ní okun. Ẹ bèèrè òjò lọ́wọ́ OLUWA ní àkókò rẹ̀, àní lọ́wọ́ OLUWA tí ó dá ìṣúdẹ̀dẹ̀ òjò; Òun ló ń fún eniyan ní ọ̀wààrà òjò, tí àwọn ohun ọ̀gbìn fi ń tutù yọ̀yọ̀. Ìsọkúsọ ni àwọn ère ń sọ, àwọn aríran ń ríran èké; àwọn tí ń lá àlá ń rọ́ àlá irọ́, wọ́n sì ń tu àwọn eniyan ninu lórí òfo. Nítorí náà ni àwọn eniyan fi ń rìn káàkiri bí aguntan tí kò ní olùṣọ́. OLUWA ní, “Inú mi ru sí àwọn olùṣọ́-aguntan, n óo sì fìyà jẹ àwọn alákòóso. Nítorí èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ń tọ́jú agbo mi, àní àwọn eniyan Juda, wọn yóo sì dàbí ẹṣin alágbára lójú ogun. Ninu wọn ni a óo ti rí òkúta igun ilé, tí a lè pè ní olórí, aṣaaju, ati aláṣẹ, láti ṣe àkóso àwọn eniyan mi. Gbogbo wọn óo jẹ́ akikanju lójú ogun, wọn óo tẹ àwọn ọ̀tá wọn mọ́lẹ̀ ní ìgboro; wọn óo jagun, nítorí OLUWA wà pẹlu wọn, wọn óo sì dá àyà já àwọn tí wọn ń gun ẹṣin. “N óo sọ ilé Juda di alágbára, n óo sì gba ilé Josẹfu là. N óo mú wọn pada, nítorí àánú wọn ń ṣe mí, wọn yóo dàbí ẹni pé n kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ rí; nítorí èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn, n óo sì gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ wọn. Nígbà tó bá yá, ilé Efuraimu yóo dàbí jagunjagun alágbára, inú wọn yóo sì dùn bí inú ẹni tí ó mu ọtí waini. Nígbà tí àwọn ọmọ wọn bá rí i, inú wọn yóo dùn, ọkàn wọn yóo sì yin OLUWA. “N óo ṣẹ́wọ́ sí wọn, n óo sì kó wọn jọ sinu ilé. Mo ti rà wọ́n pada, nítorí náà wọn yóo tún pọ̀ bíi ti àtẹ̀yìnwá. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti fọ́n wọn ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, sibẹsibẹ, wọn yóo ranti mi lọ́nà jíjìn tí wọ́n wà. Àwọn ati àwọn ọmọ wọn yóo wà láàyè, wọn yóo sì pada wá sí ilẹ̀ wọn. N óo kó wọn pada sí ilẹ̀ wọn láti ilẹ̀ Ijipti wá, n óo kó wọn jọ láti ilẹ̀ Asiria; n óo sì kó wọn wá sí ilẹ̀ Gileadi ati ilẹ̀ Lẹbanoni, wọn óo kún ilẹ̀ náà tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi ní sí ààyè mọ́. Wọn óo la òkun Ijipti kọjá, ìgbì rẹ̀ yóo sì dákẹ́ jẹ́ẹ́. Odò Naili yóo gbẹ kanlẹ̀, a óo rẹ ìgbéraga ilẹ̀ Asiria sílẹ̀, agbára óo sì kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti. N óo sọ wọ́n di alágbára ninu èmi OLUWA, wọn yóo sì máa ṣògo ninu orúkọ mi.” Ṣílẹ̀kùn rẹ, ìwọ ilẹ̀ Lẹbanoni kí iná lè jó àwọn igi kedari rẹ! Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin igi Sipirẹsi, nítorí igi kedari ti ṣubú, àwọn igi ológo ti parun. Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin igi oaku ní Baṣani, nítorí pé, a ti gé àwọn igi igbó dídí Baṣani lulẹ̀! Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, kí ẹ gbọ́ ẹkún àwọn darandaran, nítorí ògo wọn ti díbàjẹ́. Ẹ gbọ́ bí àwọn kinniun ti ń bú ramúramù, nítorí igbó tí wọn ń gbé lẹ́bàá odò Jọdani ti parun! Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA, Ọlọrun mi sọ; ó ní, “Fi ara rẹ sí ipò olùṣọ́-aguntan tí ó da àwọn ẹran rẹ̀ lọ sí ibi tí wọ́n ti pa wọ́n. Àwọn tí wọ́n rà wọ́n pa wọ́n ní àpagbé; àwọn tí wọn n tà wọ́n sì wí pé, ‘Ìyìn ni fún OLUWA, mo ti di ọlọ́rọ̀’; àwọn tí wọ́n ni wọ́n kò tilẹ̀ ṣàánú wọn.” OLUWA ní, “Bẹ́ẹ̀ gan-an ni n kò ní ṣàánú àwọn eniyan ilẹ̀ yìí mọ́. Fúnra mi ni n óo fi wọ́n lé àwọn aláṣẹ ati àwọn ọba wọn lọ́wọ́. Wọn óo run ilẹ̀ náà, n kò sì ní gba ẹnikẹ́ni lọ́wọ́ wọn.” Mo ti di darandaran agbo ẹran tí à ń dà lọ fún àwọn alápatà. Mo mú ọ̀pá meji, mo sọ ọ̀kan ní “Oore-ọ̀fẹ́,” mo sì sọ ekeji ní “Ìṣọ̀kan.” Inú mi ru sí mẹta ninu àwọn darandaran tí wọ́n kórìíra mi, mo sì mú wọn kúrò láàrin oṣù kan. Mo wá sọ fún àwọn agbo ẹran náà pé, “N kò ní ṣe olùṣọ́ yín mọ́. Èyí tí yóo bá kú ninu yín kí ó kú, èyí tí yóo bá ṣègbé, kí ó ṣègbé, kí àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù sì máa pa ara wọn jẹ.” Mo bá mú ọ̀pá mi tí ń jẹ́ “Oore-ọ̀fẹ́,” mo dá a, mo fi fi òpin sí majẹmu tí mo bá àwọn orílẹ̀-èdè dá. Nítorí náà, majẹmu mi ti dópin lọ́jọ́ náà. Àwọn tí wọn ń ṣòwò aguntan, tí wọn ń wò mí, mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo ṣe ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀. Nígbà náà ni mo wí fún wọn pé, “Bí ó bá tọ́ lójú yín, ẹ fún mi ní owó iṣẹ́ mi, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ máa mú un lọ.” Wọ́n bá wọn ọgbọ̀n owó fadaka fún mi gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́ mi. Nígbà náà ni OLUWA sọ fún mi pé, “Lọ pa owó náà mọ́ sílé ìṣúra.” Nítorí náà, mo da ọgbọ̀n owó fadaka tí wọ́n san fún mi, sinu ilé ìṣúra ní ilé OLUWA. Nígbà náà ni mo dá ọ̀pá mi keji tí ń jẹ́ “Ìṣọ̀kan,” mo fi fi òpin sí àjọṣe tí ó wà láàrin Juda ati Israẹli. OLUWA tún sọ fún mi pé “Tún fi ara rẹ sí ipò darandaran tí kò wúlò fún nǹkankan. Wò ó! N óo gbé darandaran kan dìde tí kò ní bìkítà fún àwọn ẹran tí wọ́n ń ṣègbé, kò ní tọpa àwọn tí wọn ń ṣáko lọ, tabi kí ó wo àwọn tí ń ṣàìsàn sàn, tabi kí ó fún àwọn tí ara wọn le ní oúnjẹ. Dípò kí ó tọ́jú wọn, pípa ni yóo máa pa àwọn tí ó sanra jẹ, tí yóo sì máa fa pátákò wọn ya. Olùṣọ́-aguntan mi tí kò bá níláárí gbé! Tí ó ń fi agbo ẹran sílẹ̀. Idà ni yóo ṣá a ní apá, yóo sì bá a ní ojú ọ̀tún, apá rẹ̀ óo rọ patapata, ojú ọ̀tún rẹ̀ óo sì fọ́ patapata.” Iṣẹ́ tí OLUWA rán sí Israẹli nìyí, OLUWA tí ó ta ọ̀run bí aṣọ, tí ó dá ayé, tí ó sì dá ẹ̀mí sinu eniyan, ni ó sọ báyìí pé, “N óo ṣe ìlú Jerusalẹmu bí ife ọtí àmutagbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní àyíká rẹ̀. Wọn óo dojú kọ ilẹ̀ Juda, wọn óo sì dóti ìlú Jerusalẹmu. Ṣugbọn ní ọjọ́ náà, n óo mú kí ilẹ̀ Jerusalẹmu le kankan bí òkúta tí ó wúwo, orílẹ̀-èdè tí ó bá dábàá pé òun óo ṣí i nídìí, yóo farapa yánnayànna. Gbogbo orílẹ̀-èdè yóo sì parapọ̀ láti bá a jà. Ní ọjọ́ náà, n óo dẹ́rùba àwọn ẹṣin, n óo sì fi wèrè kọlu àwọn tí wọn ń gùn wọ́n. Ṣugbọn n óo máa ṣọ́ àwọn ará Juda, n óo sì fọ́ ojú ẹṣin àwọn ọ̀tá wọn. Àwọn ará Juda yóo wá máa sọ láàrin ara wọn pé, ‘OLUWA, àwọn ọmọ ogun ti sọ àwọn ará Jerusalẹmu di alágbára.’ “Ní ọjọ́ náà, n óo jẹ́ kí àwọn ará Juda dàbí ìkòkò iná tí ń jó ninu igbó, àní, bí iná tí ń jó láàrin oko ọkà, wọn yóo jó gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri, ṣugbọn Jerusalẹmu yóo wà láàyè rẹ̀ pẹlu gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀. “OLUWA yóo kọ́kọ́ fún àwọn ogun Juda ní ìṣẹ́gun, kí ògo ilé Dafidi ati ògo àwọn ará Jerusalẹmu má baà ju ti Juda lọ. Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo dáàbò bo àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu, ẹni tí ó ṣe aláìlera jùlọ ninu wọn yóo lágbára bíi Dafidi. Ìdílé Dafidi yóo dàbí Ọlọrun, yóo máa darí wọn bí angẹli OLUWA. Ní ọjọ́ náà, n óo run àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n bá gbógun ti ìlú Jerusalẹmu. “N óo fi ẹ̀mí àánú ati adura sí ọkàn àwọn ọmọ Dafidi ati àwọn ará Jerusalẹmu, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo jẹ́ pé, bí wọ́n bá wo ẹni tí wọ́n gún lọ́kọ̀, wọn yóo máa ṣọ̀fọ̀ bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ kanṣoṣo. Wọn yóo sì sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn bí ẹni tí àkọ́bí rẹ̀ ṣàìsí. Ní àkókò náà, ọ̀fọ̀ àwọn ará Jerusalẹmu yóo pọ̀ bí ọ̀fọ̀ tí wọ́n ṣe fún Hadadi Rimoni ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Megido. Ìdílé kọ̀ọ̀kan ní ilẹ̀ náà yóo ṣọ̀fọ̀ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀; ìdílé Dafidi yóo dá ọ̀fọ̀ tirẹ̀ ṣe, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn iyawo wọn yóo ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀. Ìdílé Natani náà yóo ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀, bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn iyawo wọn, àwọn náà óo ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀. Ìdílé Lefi yóo ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn iyawo wọn, àwọn náà óo ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀. Ìdílé Ṣimei pàápàá yóo ṣọ̀fọ̀ tirẹ̀ lọ́tọ̀, àwọn iyawo wọn yóo ṣọ̀fọ̀ tiwọn náà lọ́tọ̀; gbogbo àwọn ìdílé yòókù ni wọn yóo ṣọ̀fọ̀ tiwọn náà ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àwọn iyawo wọn náà yóo sì ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀.” OLUWA ní, “Nígbà tó bá yá, orísun omi kan yóo ṣí sílẹ̀ fún ilé Dafidi, ati fún àwọn ará Jerusalẹmu láti wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ ati ìwà èérí wọn. “N óo gbá àwọn oriṣa kúrò ní ilẹ̀ náà débi pé ẹnikẹ́ni kò ní ranti wọn mọ́; bákan náà ni n óo mú gbogbo àwọn tí wọn ń pe ara wọn ní wolii kúrò, ati àwọn ẹ̀mí àìmọ́. Bí ẹnikẹ́ni bá pe ara rẹ̀ ní wolii, baba ati ìyá rẹ̀ tí ó bí i yóo wí fún un pé yóo kú, nítorí ó ń purọ́ ní orúkọ OLUWA. Bí ó bá sọ àsọtẹ́lẹ̀, baba ati ìyá rẹ̀ yóo gún un pa. Nígbà tí àkókò bá tó, ojú yóo ti olukuluku wolii fún ìran tí ó rí nígbà tí ó bá ń sọ àsọtẹ́lẹ̀, kò sì ní wọ aṣọ onírun mọ́ láti fi tan eniyan jẹ. Ṣugbọn yóo sọ pé, ‘Èmi kì í ṣe wolii, àgbẹ̀ ni mí; oko ni mò ń ro láti ìgbà èwe mi.’ Bí ẹnikẹ́ni bá bi í pé, ‘Àwọn ọgbẹ́ wo wá ni ti ẹ̀yìn rẹ?’ Yóo dáhùn pé, ‘Ọgbẹ́ tí mo gbà nílé àwọn ọ̀rẹ́ mi ni.’ ” OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Ìwọ idà, kọjú ìjà sí olùṣọ́ àwọn aguntan mi, ati sí ẹni tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi. Kọlu olùṣọ́-aguntan, kí àwọn aguntan lè fọ́nká; n óo kọjú ìjà sí àwọn aguntan kéékèèké. Jákèjádò ilẹ̀ náà, ìdá meji ninu mẹta àwọn eniyan náà ni wọn yóo kú, a óo sì dá ìdá kan yòókù sí. N óo da ìdá kan yòókù yìí sinu iná, n óo fọ̀ wọ́n mọ́, bí a tíí fi iná fọ fadaka. N óo sì dán wọn wò, bí a tíí dán wúrà wò. Wọn yóo pe orúkọ mi, n óo sì dá wọn lóhùn. N óo wí pé, ‘Eniyan mi ni wọ́n’; àwọn náà yóo sì jẹ́wọ́ pé, ‘OLUWA ni Ọlọrun wa.’ ” Wò ó! Ọjọ́ OLUWA ń bọ̀ tí wọn yóo pín àwọn ìkógun tí wọ́n kó ní ilẹ̀ Jerusalẹmu lójú yín. Nítorí n óo kó àwọn orílẹ̀-èdè jọ láti gbógun ti ìlú Jerusalẹmu. Wọn yóo ṣẹgun rẹ̀, wọn yóo kó àwọn eniyan ibẹ̀ lẹ́rù lọ, wọn yóo sì fi tipátipá bá àwọn obinrin wọn lòpọ̀. Ìdajì àwọn ará ìlú náà yóo lọ sóko ẹrú, ṣugbọn ìdajì yòókù ninu wọn yóo wà láàrin ìlú. OLUWA yóo wá jáde, yóo bá àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi jà, bí ìgbà tí ó ń jà lójú ogun. Tó bá di àkókò náà, yóo dúró lórí òkè olifi tí ó wà ní apá ìlà oòrùn Jerusalẹmu; òkè olifi yóo sì pín sí meji. Àfonífojì tí ó gbòòrò yóo sì wà láàrin rẹ̀ láti apá ìlà oòrùn dé apá ìwọ̀ oòrùn. Apá kan òkè náà yóo lọ ìhà àríwá, apá keji yóo sì lọ sí ìhà gúsù. Ẹ óo sá àsálà gba ọ̀nà pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí ó pín òkè náà sí meji. Ẹ óo sá bí àwọn baba ńlá yín ti sá nígbà tí ilẹ̀ mì tìtì ní àkókò Usaya, ọba Juda, OLUWA, Ọlọrun yín yóo wá dé, pẹlu gbogbo àwọn eniyan mímọ́ rẹ̀. Tó bá di ìgbà náà, kò ní sí òtútù tabi òjò dídì mọ́, kò ní sí òkùnkùn, kò ní sí ọ̀sán, kò ní sí òru bíkòṣe ìmọ́lẹ̀ nígbà gbogbo. Ṣugbọn OLUWA nìkan ló mọ ìgbà tí nǹkan wọnyi yóo ṣẹlẹ̀. Tó bá di ìgbà náà, àwọn odò tí wọ́n kún fún omi ìyè yóo máa ṣàn jáde láti Jerusalẹmu. Apá kan wọn yóo máa ṣàn lọ sinu òkun tí ó wà ní ìwọ̀ oòrùn, apá keji yóo máa ṣàn lọ sí òkun tí ó wà ní ìlà oòrùn, yóo sì máa rí bẹ́ẹ̀ tòjò-tẹ̀ẹ̀rùn. OLUWA yóo wá jọba ní gbogbo ayé; Ọlọrun nìkan ni gbogbo aráyé yóo máa sìn nígbà náà, orúkọ kanṣoṣo ni wọn yóo sì mọ̀ ọ́n. A óo sọ gbogbo ilẹ̀ náà di pẹ̀tẹ́lẹ̀, láti Geba ní ìhà àríwá, títí dé Rimoni ní ìhà gúsù. Ṣugbọn Jerusalẹmu yóo yọ kedere láàrin àwọn ilẹ̀ tí ó yí i ká, láti ẹnubodè Bẹnjamini, lọ dé ẹnubodè àtijọ́ ati dé ẹnubodè Igun, láti ilé-ìṣọ́ Hananeli dé ibi tí wọ́n ti ń pọn ọtí fún ọba. Àwọn eniyan yóo máa gbé inú ìlú Jerusalẹmu, kò ní sí ègún mọ́, ìlú Jerusalẹmu yóo sì wà ní alaafia. Àjàkálẹ̀ àrùn tí OLUWA yóo fi bá àwọn tí wọ́n bá gbógun ti ilẹ̀ Jerusalẹmu jà nìyí: Ẹran ara wọn yóo rà nígbà tí wọ́n ṣì wà láàyè, ojú wọn yóo rà ninu ihò rẹ̀, ahọ́n wọn yóo sì rà lẹ́nu wọn. Tó bá di ìgbà náà, OLUWA yóo mú ìbẹ̀rùbojo bá wọn tóbẹ́ẹ̀ tí wọn yóo fi máa pa ara wọn; Àwọn ará Juda pàápàá yóo máa bá àwọn ará Jerusalẹmu jà. A óo kó ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí i ká jọ: ati fadaka, ati wúrà, ati ọpọlọpọ aṣọ. Àjàkálẹ̀ àrùn burúkú náà yóo kọlu àwọn ẹṣin, ìbakasíẹ, ràkúnmí, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati gbogbo àwọn ẹran tí wọ́n bá wà ní ibùdó ogun wọn. Àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù láti àwọn orílẹ̀-èdè gbogbo tí ó gbógun ti ilẹ̀ Jerusalẹmu yóo máa wá lọdọọdun láti sin Ọba, OLUWA àwọn ọmọ ogun, ní ìlú Jerusalẹmu ati láti ṣe Àjọ̀dún Àgọ́. Bí ẹnikẹ́ni bá kọ̀ tí kò lọ sí ìlú Jerusalẹmu lọ sin Ọba, OLUWA àwọn ọmọ ogun, òjò kò ní rọ̀ sí ilẹ̀ rẹ̀. Bí ó bá ṣe pé àwọn ará Ijipti ni wọ́n kọ̀ tí wọn kò wá síbi Àjọ̀dún Àgọ́ náà, irú àrùn tí OLUWA fi bá àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò wá sí ibi Àjọ Àgọ́ jà, ni yóo dà lé wọn lórí. Èyí ni ìyà tí yóo jẹ ilẹ̀ Ijipti ati gbogbo orílẹ̀-èdè tí kò bá wá síbi Àjọ Àgọ́. Tó bá di ìgbà náà, a óo máa kọ “MÍMỌ́ SÍ OLUWA,” sí ara aago tí wọn ń so mọ́ ẹṣin lára. Ìkòkò inú ilé OLUWA, yóo sì máa dàbí àwọn àwo tí ó wà níwájú pẹpẹ. Gbogbo ìkòkò tí ó wà ní Jerusalẹmu ati ní Juda yóo di mímọ́ fún OLUWA àwọn ọmọ ogun. Àwọn tí wọ́n wá ṣe ìrúbọ yóo máa se ẹran ẹbọ wọn ninu ìkòkò wọnyi. Kò ní sí oníṣòwò ní ilé OLUWA àwọn ọmọ ogun mọ́ tó bá di ìgbà náà. Iṣẹ́ tí OLUWA rán wolii Malaki sí àwọn ọmọ Israẹli nìyí. OLUWA ní, “Mo fẹ́ràn yín pupọ.” Ṣugbọn ẹ̀ ń bèèrè pé, “Kí ló fihàn pé o fẹ́ràn wa?” OLUWA dáhùn pé, “Ṣebí tẹ̀gbọ́n-tàbúrò ni Esau ati Jakọbu? Sibẹ mo fẹ́ràn Jakọbu, mo sì kórìíra Esau. Mo ti sọ gbogbo àwọn ìlú òkè Esau di ahoro, mo sì sọ ilẹ̀ ìní rẹ̀ di ilé ajáko tí ó wà ní aṣálẹ̀.” Bí Edomu bá sọ pé, “Ìlú wa ti di òkítì àlàpà, ṣugbọn a óo tún un kọ́.” Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo wá dáhùn pé, “Wọ́n lè máa kọ́ ọ, ṣugbọn n óo tún máa wó o lulẹ̀ títí tí àwọn eniyan yóo fi máa pè wọ́n ní orílẹ̀-èdè burúkú, àwọn ẹni tí OLUWA bínú sí títí lae.” Ẹ óo fi ojú ara yín rí i ẹ óo sì sọ pé, “OLUWA tóbi lọ́ba, kódà títí dé ilẹ̀ tí kì í ṣe ilẹ̀ Israẹli!” “Ọmọ a máa bọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀, iranṣẹ a sì máa bẹ̀rù oluwa rẹ̀. Bí mo bá jẹ́ baba yín, ṣé ẹ̀ ń bọ̀wọ̀ fún mi? Bí mo bá sì jẹ́ oluwa yín, ṣé ẹ bẹ̀rù mi ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ń bi ẹ̀yin alufaa tí ẹ̀ ń tàbùkù orúkọ mi? Sibẹsibẹ ẹ̀ ń bèèrè pé, ‘Ọ̀nà wo ni a fi ń tàbùkù orúkọ rẹ?’ Ìdí rẹ̀ tí mo fi ní ẹ̀ ń tàbùkù orúkọ mi ni pé, ẹ̀ ń fi oúnjẹ àìmọ́ rúbọ lórí pẹpẹ mi. Ẹ tún bèèrè pé, ‘Ọ̀nà wo ni a fi sọ pẹpẹ rẹ di àìmọ́?’ Ẹ ti tàbùkù pẹpẹ mi, nípa rírò pé ẹ lè tàbùkù rẹ̀. Nígbà tí ẹ bá mú ẹran tí ó fọ́jú, tabi ẹran tí ó múkùn-ún, tabi ẹran tí ń ṣàìsàn wá rúbọ sí mi, ǹjẹ́ kò burú? Ṣé ẹ lè fún gomina ní irú rẹ̀ kí inú rẹ̀ dùn si yín, tabi kí ẹ rí ojurere rẹ̀?” Nisinsinyii, ẹ̀yin alufaa, ẹ mú irú ọrẹ bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́, ẹ̀ ń gbadura sí Ọlọrun, pé kí ó lè fi ojurere wò yín; Ṣé ẹ rò pé OLUWA yóo fi ojurere wo ẹnikẹ́ni ninu yín? Ìbá ti dára tó kí ẹnìkan ninu yín ti ìlẹ̀kùn tẹmpili pa, kí ẹ má baà máa wá tanná mọ́, kí ẹ máa rú ẹbọ asán lórí pẹpẹ mi! Inú mi kò dùn si yín, n kò sì ní gba ọrẹ tí ẹ mú wá. Nítorí pé, jákèjádò gbogbo ayé, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀ ni orúkọ mi ti tóbi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, ibi gbogbo ni wọ́n sì ti ń sun turari sí mi, tí wọ́n sì ń rú ẹbọ mímọ́ sí mi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè. Ṣugbọn ẹ tàbùkù orúkọ mi nígbà tí ẹ sọ pé pẹpẹ OLUWA ti di àìmọ́, tí ẹ sì ń fi oúnjẹ tí ẹ pẹ̀gàn rúbọ lórí rẹ̀. Ẹ̀ ń sọ pé, “Èyí sú wa!” Ẹ̀ ń yínmú sí mi. Ẹran tí ẹ fi ipá gbà, tabi èyí tí ó yarọ, tabi èyí tí ń ṣàìsàn ni ẹ̀ ń mú wá láti fi rúbọ. Ṣé ẹ rò pé n óo gba irú ẹbọ bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ yín? Ègún ni fún arẹ́nijẹ; tí ó jẹ́jẹ̀ẹ́ akọ ẹran láti inú agbo rẹ̀, ṣugbọn tí ó fi ẹran tí ó ní àbùkù rúbọ sí OLUWA. Ọba ńlá ni mí, gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni wọ́n sì bẹ̀rù orúkọ mi. OLUWA ní, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin alufaa, ẹ̀yin ni àṣẹ yìí wà fún. Bí ẹ kò bá ní gbọ́ràn, tí ẹ kò sì ní fi sọ́kàn láti fi ògo fún orúkọ mi, n óo mú ègún wá sórí yín, ati sórí àwọn ohun ìní yín. Mo tilẹ̀ ti mú ègún wá sórí àwọn ohun ìní yín, nítorí pé ẹ kò fi ọ̀rọ̀ mi sọ́kàn. Ẹ wò ó! N óo jẹ àwọn ọmọ yín níyà, n óo fi ìgbẹ́ ẹran tí ẹ fi ń rúbọ kùn yín lójú, n óo sì le yín kúrò níwájú mi. Nígbà náà ni ẹ óo mọ̀ pé èmi ni mo pàṣẹ yìí fun yín, kí majẹmu mi pẹlu Lefi má baà yẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun wí! “Majẹmu ìyè ati alaafia ni majẹmu mi pẹlu Lefi. Mo bá a dá majẹmu yìí kí ó baà lè bẹ̀rù mi; ó sì bẹ̀rù mi, ó bọ̀wọ̀ fún orúkọ mi. Ó fi ẹ̀kọ́ òtítọ́ kọ́ni, kìí sọ̀rọ̀ àìtọ́. Ó bá mi rìn ní alaafia ati ìdúróṣinṣin, ó sì yí ọkàn ọpọlọpọ eniyan pada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀. Láti ẹnu alufaa ni ó ti yẹ kí ìmọ̀ ti máa jáde, kí àwọn eniyan sì máa gba ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí pé, iranṣẹ OLUWA àwọn ọmọ ogun ni. “Ṣugbọn ẹ̀yin alufaa ti yapa kúrò ní ọ̀nà òtítọ́, ẹ ti mú ọ̀pọ̀ eniyan kọsẹ̀ nípa ẹ̀kọ́ yín, ẹ sì ti da majẹmu tí mo bá Lefi dá. Nítorí náà, n óo pa yín dà sí àìdára, ẹ óo sì di yẹpẹrẹ lójú àwọn eniyan; nítorí pé ẹ kò tẹ̀lé ìlànà mi, ẹ̀ ń fi ojuṣaaju bá àwọn eniyan lò nígbà tí ẹ bá ń kọ́ wọn. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí!” Ṣebí baba kan náà ló bí wa? Ṣebí Ọlọrun kan náà ló dá wa? Kí ló dé tí a fi ń ṣe aiṣootọ sí ara wa, tí a sì ń sọ majẹmu àwọn baba wa di aláìmọ́? Àwọn ará Juda jẹ́ alaiṣootọ sí OLUWA, àwọn eniyan ti ṣe ohun ìríra ní Israẹli ati ní Jerusalẹmu. Àwọn ará Juda ti sọ ibi mímọ́ tí OLUWA fẹ́ràn di aláìmọ́; àwọn ọmọkunrin wọn sì ti fẹ́ àjèjì obinrin, ní ìdílé abọ̀rìṣà. Kí OLUWA yọ irú eniyan bẹ́ẹ̀ kúrò ní àwùjọ Jakọbu, kí ó má lè jẹ́rìí tabi kí ó dáhùn sí ohun tíí ṣe ti OLUWA, kí ó má sì lọ́wọ́ ninu ẹbọ rírú sí OLUWA àwọn ọmọ ogun mọ́ lae! Ohun mìíràn tí ẹ tún ń ṣe nìyí. Ẹ̀ ń sọkún, omijé ojú yín ń ṣàn lára pẹpẹ OLUWA, ẹ̀ ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ sì ń ké, nítorí pé OLUWA kò gba ọrẹ tí ẹ mú wá fún un. Ẹ̀ ń bèèrè pé, “Kí ló dé tí kò fi gbà á?” Ìdí rẹ̀ ni pé, OLUWA ni ẹlẹ́rìí majẹmu tí ẹ dá pẹlu aya tí ẹ fẹ́ nígbà èwe yín, tí ẹ sì ṣe aiṣootọ sí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé olùrànlọ́wọ́ yín ni, òun sì ni aya tí ẹ bá dá majẹmu. Ṣebí ara kan náà ati ẹ̀jẹ̀ kan náà ni Ọlọrun ṣe ìwọ pẹlu rẹ̀? Kí ló dé tí Ọlọrun fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí rẹ̀ ni pé, Ọlọrun ń fẹ́ irú ọmọ tí yóo jẹ́ tirẹ̀. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra yín, kí ẹ má ṣe hùwà aiṣootọ sí aya tí ẹ fẹ́ nígbà èwe yín. “Mo kórìíra ìkọ̀sílẹ̀ láàrin tọkọtaya, mo kórìíra irú ìwà ìkà bẹ́ẹ̀ sí olólùfẹ́ ẹni. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má ṣe jẹ́ alaiṣootọ sí aya yín. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí!” Ọ̀rọ̀ yín ti sú Ọlọrun, sibẹsibẹ ẹ̀ ń bèèrè pé, “Báwo ni a ṣe mú kí ọ̀rọ̀ wa sú u?” Nítorí ẹ̀ ń sọ pé, “Gbogbo àwọn tí wọn ń ṣe burúkú jẹ́ eniyan rere níwájú OLUWA, inú rẹ̀ sì dùn sí wọn.” Tabi nípa bíbèèrè pé, “Níbo ni Ọlọrun onídàájọ́ òdodo wà?” OLUWA ní, “Wò ó! Mo rán òjíṣẹ́ mi ṣiwaju mi láti tún ọ̀nà ṣe fún mi. OLUWA tí ẹ sì ń retí yóo yọ lójijì sinu tẹmpili rẹ̀; iranṣẹ mi, tí ẹ sì tí ń retí pé kí ó wá kéde majẹmu mi, yóo wá.” Ṣugbọn, ta ló lè farada ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ tí ó bá dé? Àwọn wo ni wọn yóo lè dúró ní ọjọ́ tí ó bá yọ? Nítorí pé ó dàbí iná alágbẹ̀dẹ tí ń yọ́ irin, ati bí ọṣẹ alágbàfọ̀ tí ń fọ nǹkan mọ́. Yóo jókòó bí ẹni tí ń yọ́ fadaka, yóo fọ àwọn ọmọ Lefi mọ́ bíi wúrà ati fadaka, títí tí wọn yóo fi mú ẹbọ tí ó tọ́ wá fún OLUWA. Inú OLUWA yóo wá dùn sí ẹbọ Juda ati ti Jerusalẹmu nígbà náà bíi ti àtẹ̀yìnwá. OLUWA ní, “N óo wá ba yín láti ṣe ìdájọ́; n óo wá jẹ́rìí mọ́ àwọn oṣó ati àwọn alágbèrè, àwọn tí wọn ń búra èké ati àwọn tí wọn kì í san owó ọ̀yà pé, àwọn tí wọn ń ni àwọn opó ati àwọn aláìníbaba lára, ati àwọn tí wọn ń ṣi àwọn àlejò lọ́nà, tí wọn kò sì bẹ̀rù mi.” OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Nítorí pé èmi OLUWA kì í yipada, ni a kò fi tíì run ẹ̀yin ọmọ Jakọbu patapata. Láti ayé àwọn baba ńlá yín ni ẹ ti yapa kúrò ninu ìlànà mi, tí ẹ kò sì tẹ̀lé wọn mọ́. Ẹ̀yin ẹ yipada sí mi, èmi náà óo sì yipada si yín. Ṣugbọn ẹ̀ ń bèèrè pé, ‘Báwo ni a ti ṣe lè yipada?’ Ǹjẹ́ ó ṣeéṣe fún eniyan láti ja Ọlọrun lólè? Ṣugbọn ẹ̀ ń jà mí lólè. Ẹ sì ń bèèrè pé, ‘Ọ̀nà wo ni à ń gbà jà ọ́ lólè?’ Nípa ìdámẹ́wàá ati ọrẹ yín ni. Ègún wà lórí gbogbo yín nítorí pé gbogbo orílẹ̀-èdè yín ní ń jà mí lólè. Ẹ mú gbogbo ìdámẹ́wàá yín wá sí ilé ìṣúra, kí oúnjẹ baà lè wà ninu ilé mi. Ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ kí ẹ fi dán mi wò, bí n kò bá ní ṣí fèrèsé ọ̀run sílẹ̀, kí n sì tú ibukun jáde fun yín lọpọlọpọ, tóbẹ́ẹ̀ tí kò ní sí ààyè tó láti gbà á. N kò ní jẹ́ kí kòkòrò ajẹnirun jẹ ohun ọ̀gbìn yín lóko, ọgbà àjàrà yín yóo sì so jìnwìnnì. Nígbà náà ni àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa pè yín ní ẹni ibukun, ilẹ̀ yín yóo sì jẹ́ ilẹ̀ ayọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí!” OLUWA ní, “Ẹ ti fi ẹnu yín sọ ọ̀rọ̀ burúkú sí mi. Sibẹsibẹ ẹ̀ ń wí pé, ‘Irú ọ̀rọ̀ burúkú wo ni a sọ sí ọ?’ Ẹ sọ pé, ‘Kí eniyan máa sin Ọlọrun kò jámọ́ nǹkankan. Kò sì sí èrè ninu pípa òfin rẹ̀ mọ́ tabi ninu rírẹ ara wa sílẹ̀ níwájú OLUWA àwọn ọmọ ogun. Ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nisinsinyii ni pé: ó ń dára fún àwọn agbéraga; kì í sì í ṣe pé ó ń dára fún àwọn eniyan burúkú nìkan, ṣugbọn nígbà tí wọ́n bá fi ìwà burúkú wọn dán Ọlọrun wò, kò sí nǹkankan tí ń ṣẹlẹ̀ sí wọn.’ ” Nígbà tí àwọn tí wọ́n bẹ̀rù OLUWA bá ń bá ara wọn sọ̀rọ̀, OLUWA a máa tẹ́tí sí wọn, yóo sì gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn. Ó ní ìwé kan níwájú rẹ̀ ninu èyí tí àkọsílẹ̀ àwọn tí wọ́n bẹ̀rù OLUWA, tí wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ̀ wà. OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Wọn yóo jẹ́ eniyan mi, ní ọjọ́ tí mo bá fi agbára mi hàn, wọn yóo jẹ́ ohun ìní mi pataki. N óo ṣàánú fún wọn bí baba tií ṣàánú fún ọmọ rẹ̀ tí ń sìn ín. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ẹ óo tún rí ìyàtọ̀ láàrin àwọn eniyan rere tí wọn ń sin Ọlọrun, ati àwọn ẹni ibi tí wọn kì í sìn ín.” OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Wò ó! Ọjọ́ náà ń bọ̀ bí iná ìléru, tí àwọn agbéraga ati àwọn oníṣẹ́ ibi yóo jóná bíi koríko gbígbẹ. Ráúráú ni wọn óo jóná. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí! Ṣugbọn ní ti ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù mi, oòrùn òdodo yóo tàn si yín pẹlu ìwòsàn mi, ẹ óo máa yan káàkiri bí ọmọ ẹran tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ tú sílẹ̀. Ẹ óo tẹ àwọn eniyan burúkú mọ́lẹ̀, nítorí wọn yóo di eérú lábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ yín, ní ọjọ́ tí mo bá fi agbára mi hàn. “Ẹ ranti òfin ati ìlànà tí mo ti fún Mose, iranṣẹ mi, fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ní orí òkè Horebu. “Ẹ wò ó! N óo rán wolii Elija si yín kí ọjọ́ ńlá OLUWA, tí ó bani lẹ́rù náà tó dé. Yóo yí ọkàn àwọn baba pada sọ́dọ̀ àwọn ọmọ wọn, yóo sì yí ti àwọn ọmọ, pada sọ́dọ̀ àwọn baba wọn; kí n má baà fi ilẹ̀ náà gégùn-ún.” Èyí ni àkọsílẹ̀ ìran Jesu Kristi, ọmọ Dafidi, ọmọ Abrahamu. Abrahamu bí Isaaki, Isaaki bí Jakọbu, Jakọbu bí Juda ati àwọn arakunrin rẹ̀. Juda bí Peresi ati Sera, ìyá wọn ni Tamari. Peresi bí Hesironi, Hesironi bí Ramu. Ramu bí Aminadabu, Aminadabu bí Naṣoni, Naṣoni bí Salimoni. Salimoni bí Boasi, ìyá Boasi ni Rahabu, Boasi bí Obedi. Ìyá Obedi ni Rutu. Obedi bí Jese. Jese bí Dafidi ọba. Dafidi bí Solomoni. Aya Uraya tẹ́lẹ̀ ni ìyá Solomoni. Solomoni bí Rehoboamu, Rehoboamu bí Abija, Abija bí Asa. Asa bí Jehoṣafati, Jehoṣafati bí Joramu, Joramu bí Usaya. Usaya bí Jotamu, Jotamu bí Ahasi, Ahasi bí Hesekaya. Hesekaya bí Manase, Manase bí Amosi, Amosi bí Josaya. Josaya bí Jekonaya ati àwọn arakunrin rẹ̀ ní àkókò tí wọn kó àwọn ọmọ Israẹli lẹ́rú lọ sí Babiloni. Lẹ́yìn tí wọn kó wọn lẹ́rú lọ sí Babiloni, Jekonaya bí Ṣealitieli, Ṣealitieli bí Serubabeli. Serubabeli bí Abihudi, Abihudi bí Eliakimu, Eliakimu bí Asori. Asori bí Sadoku, Sadoku bí Akimu, Akimu bí Eliudi. Eliudi bí Eleasari, Eleasari bí Matani, Matani bí Jakọbu. Jakọbu bí Josẹfu ọkọ Maria, ẹni tí ó bí Jesu tí à ń pè ní Kristi. Nítorí náà, gbogbo ìran Jesu láti ìgbà Abrahamu títí di ti Dafidi jẹ́ mẹrinla; láti ìgbà Dafidi títí di ìgbà tí wọn kó àwọn ọmọ Israẹli lẹ́rú lọ sí Babiloni jẹ́ ìran mẹrinla; láti ìgbà tí wọn kó wọn lẹ́rú lọ sí Babiloni títí di àkókò Kristi jẹ́ ìran mẹrinla. Bí ìtàn ìbí Jesu Kristi ti rí nìyí. Nígbà tí Maria ìyá rẹ̀ wà ní iyawo àfẹ́sọ́nà Josẹfu, kí wọn tó ṣe igbeyawo, a rí i pé Maria ti lóyún láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. Eniyan rere ni Josẹfu ọkọ rẹ̀, kò fẹ́ dójú tì í, ó fẹ́ rọra kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní bòńkẹ́lẹ́. Bí ó ti ń ronú bí yóo ti gbé ọ̀rọ̀ náà gbà, angẹli Oluwa kan fara hàn án lójú àlá. Ó sọ fún un pé, “Josẹfu, ọmọ Dafidi, má bẹ̀rù láti mú Maria aya rẹ sọ́dọ̀, nítorí láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ ni oyún tí ó ní. Yóo bí ọmọkunrin kan, o óo sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu nítorí òun ni yóo gba àwọn eniyan rẹ̀ là kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí OLUWA ti sọ láti ẹnu wolii nì lè ṣẹ pé, “Wundia kan yóo lóyún, yóo bí ọmọkunrin kan; wọn yóo pe orúkọ rẹ̀ ní Imanuẹli.” (Ìtumọ̀, “Imanuẹli” ni “Ọlọrun wà pẹlu wa.”) Nígbà tí Josẹfu jí láti ojú oorun, ó ṣe gẹ́gẹ́ bí angẹli Oluwa náà ti pàṣẹ fún un. Ó mú iyawo rẹ̀ sọ́dọ̀. Kò sì bá a lòpọ̀ rárá títí ó fi bímọ. Ó sì pe orúkọ ọmọ náà ní Jesu. Nígbà tí wọ́n bí Jesu ní Bẹtilẹhẹmu ní ilẹ̀ Judia, ní ayé Hẹrọdu ọba, àwọn amòye kan wá sí Jerusalẹmu láti ìhà ìlà oòrùn. Wọ́n bèèrè pé, “Níbo ni ọmọ tí a bí tí yóo jẹ ọba àwọn Juu wà? A ti rí ìràwọ̀ rẹ̀ ní ìlà oòrùn, nítorí náà ni a ṣe wá láti júbà rẹ̀.” Nígbà tí Hẹrọdu gbọ́, ara rẹ̀ kò balẹ̀, ara gbogbo eniyan ìlú Jerusalẹmu náà kò sì balẹ̀. Ọba bá pe gbogbo àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin láàrin àwọn eniyan, ó wádìí nípa ibi tí a óo ti bí Kristi lọ́wọ́ wọn. Wọ́n sọ fún un pé, “Ní Bẹtilẹhẹmu ti ilẹ̀ Judia ni. Nítorí bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní àkọsílẹ̀ wolii nì pé. ‘Àní ìwọ Bẹtilẹhẹmu ilẹ̀ Juda, o kì í ṣe ìlú tí ó rẹ̀yìn jùlọ ninu àwọn olú-ìlú Juda. Nítorí láti inú rẹ ni aṣiwaju kan yóo ti jáde, tí yóo jẹ́ olùṣọ́-aguntan fún Israẹli, eniyan mi.’ ” Hẹrọdu bá pe àwọn amòye náà síkọ̀kọ̀, ó fọgbọ́n wádìí àkókò tí ìràwọ̀ náà yọ lọ́dọ̀ wọn. Ó bá rán wọn lọ sí Bẹtilẹhẹmu. Ó ní, “Ẹ lọ, kí ẹ fẹ̀sọ̀ wádìí nípa ọmọ náà. Nígbà tí ẹ bá rí i, ẹ wá ròyìn fún mi kí èmi náà lè lọ júbà rẹ̀.” Nígbà tí wọn gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba, wọ́n lọ. Bí wọ́n ti ń lọ, ìràwọ̀ tí wọ́n ti rí ní ìlà oòrùn bẹ̀rẹ̀ sí lọ níwájú wọn títí ó fi dúró ní ọ̀gangan ibi tí ọmọ náà wà. Nígbà tí wọ́n rí ìràwọ̀ náà, inú wọn dùn gan-an. Bí wọ́n ti wọlé, wọ́n rí ọmọ náà pẹlu Maria ìyá rẹ̀, wọ́n kúnlẹ̀, wọ́n sì júbà rẹ̀. Wọ́n ṣí àpótí ìṣúra wọn, wọ́n fún un ní ẹ̀bùn: wúrà, turari ati òjíá. Nítorí pé Ọlọrun ti kìlọ̀ fún wọn tẹ́lẹ̀ ní ojú àlá, wọn kò pada sọ́dọ̀ Hẹrọdu mọ́; ọ̀nà mìíràn ni wọ́n gbà pada lọ sí ìlú wọn. Lẹ́yìn tí àwọn amòye ti pada lọ, angẹli Oluwa kan fara han Josẹfu ní ojú àlá, ó sọ fún un pé, “Dìde, gbé ọmọ náà ati ìyá rẹ̀, kí o sálọ sí Ijipti, kí o sì wà níbẹ̀ títí di ìgbà tí mo bá sọ fún ọ, nítorí Hẹrọdu yóo máa wá ọmọ náà láti pa á.” Josẹfu bá dìde ní òru, ó gbé ọmọ náà ati ìyá rẹ̀, ó lọ sí Ijipti. Níbẹ̀ ni ó wà títí Hẹrọdu fi kú. Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí àsọtẹ́lẹ̀ nì lè ṣẹ pé, “Láti Ijipti ni mo ti pe ọmọ mi.” Nígbà tí Hẹrọdu rí i pé àwọn amòye tan òun jẹ ni, inú bí i pupọ. Ó bá pàṣẹ pé kí wọn máa pa gbogbo àwọn ọmọ-ọwọ́ lọkunrin ní Bẹtilẹhẹmu ati ní gbogbo agbègbè ibẹ̀ láti ọmọ ọdún meji wálẹ̀ títí di ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, gẹ́gẹ́ bí àkókò tí ó fọgbọ́n wádìí lọ́wọ́ àwọn amòye. Èyí ṣẹlẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí wolii Jeremaya sọ lè ṣẹ pé, “A gbọ́ ohùn kan ní Rama, ẹkún ati ọ̀fọ̀ gidi. Rakẹli ń sunkún nítorí àwọn ọmọ rẹ̀; ó kọ̀, kò gba ìpẹ̀, nítorí wọn kò sí mọ́.” Lẹ́yìn tí Hẹrọdu ti kú, angẹli Oluwa kan fara han Josẹfu ní ojú àlá ní Ijipti. Ó sọ fún un pé, “Dìde, gbé ọmọ náà ati ìyá rẹ́, kí o pada lọ sí ilẹ̀ Israẹli, nítorí àwọn tí wọ́n fẹ́ pa ọmọ náà ti kú.” Josẹfu bá dìde, ó gbé ọmọ náà ati ìyá rẹ̀ pada sí ilẹ̀ Israẹli. Nígbà tí Josẹfu gbọ́ pé Akelau ni ó jọba ní Judia ní ipò Hẹrọdu baba rẹ̀, ẹ̀rù bà á láti lọ sibẹ. Lẹ́yìn tí a ti kìlọ̀ fún un lójú àlá, ó yẹra níbẹ̀ lọ sí agbègbè Galili. Ó bá ń gbé ìlú kan tí à ń pé ní Nasarẹti. Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí àwọn wolii sọ lè ṣẹ pé, “A óo pè é ní ará Nasarẹti.” Nígbà tí ó yá, Johanu Onítẹ̀bọmi dé, ó ń waasu ní aṣálẹ̀ Judia. Ó ní, “Ẹ ronupiwada, nítorí ìjọba Ọlọrun fẹ́rẹ̀ dé.” Nítorí òun ni wolii Aisaya sọ nípa rẹ̀ pé, “Ohùn ẹnìkan tí ó ń kígbe ninu aṣálẹ̀ pé, ‘Ẹ la ọ̀nà tí OLUWA yóo gbà, ẹ ṣe é kí ó tọ́ fún un láti rìn.’ ” Johanu yìí wọ aṣọ tí a fi irun ràkúnmí hun, ọ̀já ìgbànú aláwọ ni ó gbà mọ́ ìdí. Oúnjẹ rẹ̀ ni ẹṣú ati oyin ìgàn. Nígbà náà ni àwọn eniyan láti Jerusalẹmu ati gbogbo ilẹ̀ Judia ati ní gbogbo ìgbèríko odò Jọdani ń jáde tọ̀ ọ́ lọ. Wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ó sì ń ṣe ìrìbọmi fún wọn ninu odò Jọdani. Ṣugbọn nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ ninu àwọn Farisi ati Sadusi tí wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pé kí ó ṣe ìrìbọmi fún wọn, ó bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fun yín láti sá fún ibinu tí ń bọ̀? Ẹ fihàn ninu ìwà yín pé ẹ ti ronupiwada. Ẹ má ṣe rò lọ́kàn yín pé, ‘A ní Abrahamu ní baba.’ Nítorí mo ń sọ fun yín pé Ọlọrun lè gbé ọmọ dìde fún Abrahamu láti inú òkúta wọnyi. A sì ti fi àáké lé gbòǹgbò igi báyìí, nítorí náà, igikígi tí kò bá so èso rere ni a óo gé lulẹ̀, tí a óo fi dáná. Ìrìbọmi ni èmi fi ń wẹ̀ yín mọ́ nítorí ìrònúpìwàdà. Ṣugbọn ẹni tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn mi jù mí lọ; èmi kò tó ẹni tí ó lè kó bàtà rẹ̀. Ẹ̀mí Mímọ́ ati iná ni òun yóo fi wẹ̀ yín mọ́. Àtẹ ìfẹ́kà rẹ̀ ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀. Yóo gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ mọ́ tótó. Yóo kó ọkà rẹ̀ jọ sinu abà, ṣugbọn sísun ni yóo sun fùlùfúlù ninu iná àjóòkú.” Nígbà náà ni Jesu lọ láti ilẹ̀ Galili, sọ́dọ̀ Johanu ní odò Jọdani, kí Johanu lè ṣe ìrìbọmi fún un. Ṣugbọn Johanu fẹ́ kọ̀ fún un, ó ní, “Èmi gan-an ni mo nílò pé kí o ṣe ìrìbọmi fún mi; ìwọ ni ó tún tọ̀ mí wá?” Jesu dá a lóhùn pé, “Jẹ́ kí á ṣe é bẹ́ẹ̀ ná, nítorí báyìí ni ó yẹ fún wa bí a bá fẹ́ ṣe ẹ̀tọ́ láṣepé.” Nígbà náà ni Johanu gbà fún un. Bí Jesu ti ṣe ìrìbọmi tán, tí ó gòkè jáde kúrò ninu omi, ọ̀run pínyà lẹsẹkẹsẹ. Jesu wá rí Ẹ̀mí Ọlọrun tí ó sọ̀kalẹ̀ bí àdàbà, tí ó ń bà lé e. Ohùn kan láti ọ̀run wá sọ pé, “Àyànfẹ́ ọmọ mi nìyí, inú mi dùn sí i gidigidi.” Lẹ́yìn náà, Ẹ̀mí gbé Jesu lọ sí aṣálẹ̀ kí Èṣù lè dán an wò. Lẹ́yìn tí ó ti gbààwẹ̀ tọ̀sán-tòru fún ogoji ọjọ́, ebi wá ń pa á. Ni adánniwò bá yọ sí i, ó sọ fún un pé, “Bí Ọmọ Ọlọrun bá ni ọ́ nítòótọ́, sọ fún àwọn òkúta wọnyi kí wọ́n di àkàrà.” Ṣugbọn Jesu dá a lóhùn pé, “Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Kì í ṣe oúnjẹ nìkan ni yóo mú kí eniyan wà láàyè, bíkòṣe nípa gbogbo ọ̀rọ̀ tí Ọlọrun bá sọ.’ ” Lẹ́yìn náà, Èṣù mú un lọ sí Jerusalẹmu, ìlú mímọ́ nì, ó gbé e lé góńgó orí Tẹmpili. Ó sọ fún un pé, “Bí Ọmọ Ọlọrun bá ni ọ́ nítòótọ́, bẹ́ sílẹ̀. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Yóo pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀ nítorí rẹ, kí wọ́n tẹ́wọ́ gbà ọ́, kí o má baà fi ẹsẹ̀ gbún òkúta.’ ” Jesu sọ fún un pé, “Ó tún wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Oluwa Ọlọrun rẹ wò.’ ” Èṣù tún mú un lọ sórí òkè gíga kan; ó fi gbogbo àwọn ìjọba ayé ati ògo wọn hàn án. Ó bá sọ fún un pé, “Gbogbo nǹkan wọnyi ni n óo fún ọ bí o bá wolẹ̀ tí o júbà mi.” Jesu bá dá a lóhùn, ó ní, “Pada kúrò lẹ́yìn mi, Satani. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Oluwa Ọlọrun rẹ ni kí o máa júbà, òun nìkan ni kí o máa sìn.’ ” Lẹ́yìn náà, Èṣù fi í sílẹ̀. Àwọn angẹli bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń ṣe iranṣẹ fún un. Nígbà tí Jesu gbọ́ pé wọ́n ti ju Johanu sẹ́wọ̀n, ó yẹra lọ sí Galili. Lẹ́yìn tí ó kúrò ní Nasarẹti, ó ń lọ gbè Kapanaumu tí ó wà lẹ́bàá òkun ní agbègbè Sebuluni ati Nafutali. Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí wolii Aisaya sọ lè ṣẹ pé: “Ilẹ̀ Sebuluni ati ilẹ̀ Nafutali, ní ọ̀nà òkun, ní òdìkejì Jọdani, Galili àwọn àjèjì. Àwọn eniyan tí ó jókòó ní òkùnkùn rí ìmọ́lẹ̀ ńlá. Ìmọ́lẹ̀ mọ́ sórí àwọn tí ó jókòó ní ilẹ̀ tí òjìji ikú wà.” Láti àkókò yìí ni Jesu ti bẹ̀rẹ̀ sí waasu pé, “Ẹ ronupiwada, nítorí ìjọba ọ̀run súnmọ́ ìtòsí.” Bí Jesu ti ń rìn lọ lẹ́bàá òkun Galili, ó rí àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò meji kan, Simoni tí ó tún ń jẹ́ Peteru ati Anderu arakunrin rẹ̀. Wọ́n ń da àwọ̀n sí inú òkun, nítorí apẹja ni wọ́n. Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ máa tẹ̀lé mi, kì í ṣe ẹja ni ẹ óo máa pamọ́, eniyan ni ẹ óo máa fà wá.” Lẹsẹkẹsẹ wọ́n bá fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. Bí ó ti kúrò níbẹ̀ tí ó lọ siwaju díẹ̀ sí i, ó rí àwọn arakunrin meji mìíràn, Jakọbu ọmọ Sebede ati Johanu arakunrin rẹ̀. Wọ́n wà ninu ọkọ̀ pẹlu Sebede baba wọn, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe. Ó bá pè wọ́n. Lẹsẹkẹsẹ, wọ́n fi ọkọ̀ ati baba wọn sílẹ̀, wọ́n tẹ̀lé e. Jesu wá ń kiri gbogbo Galili, ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu ilé ìpàdé wọn, ó ń waasu ìyìn rere ìjọba Ọlọrun, ó tún ń wo oríṣìíríṣìí àrùn sàn lára àwọn eniyan. Òkìkí rẹ̀ kàn ká gbogbo Siria. Àwọn eniyan ń gbé gbogbo àwọn tí ó ní oríṣìíríṣìí àrùn ati àìlera wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ati àwọn tí ẹ̀mí Èṣù ń dà láàmú, ati àwọn tí wárápá mú ati àwọn arọ; ó sì ń wò wọ́n sàn. Ọpọlọpọ eniyan ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn láti Galili ati Ìlú Mẹ́wàá ati Jerusalẹmu ati Judia, ati láti òdìkejì Jọdani. Nígbà tí Jesu rí ọ̀pọ̀ eniyan, ó gun orí òkè lọ. Ó jókòó; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó bá tẹnu bọ̀rọ̀, ó ń kọ́ wọn pé: “Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó jẹ́ òtòṣì ní ẹ̀mí, nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, nítorí Ọlọrun yóo tù wọ́n ninu. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀, nítorí wọn yóo jogún ayé. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ebi òdodo ń pa, tí òùngbẹ òdodo sì ń gbẹ, nítorí Ọlọrun yóo bọ́ wọn ní àbọ́yó. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn aláàánú, nítorí Ọlọrun yóo ṣàánú wọn. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ọkàn wọn mọ́, nítorí wọn yóo rí Ọlọrun. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó ń mú kí alaafia wà láàrin àwọn eniyan, nítorí Ọlọrun yóo pè wọ́n ní ọmọ rẹ̀. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí eniyan ń ṣe inúnibíni sí nítorí òdodo, nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run. “Ayọ̀ ń bẹ fun yín, tí wọ́n bá kẹ́gàn yín, tí wọ́n ṣe inúnibíni si yín, tí wọ́n bá ń fi èké sọ ọ̀rọ̀ burúkú lóríṣìíríṣìí si yín nítorí mi. Ẹ máa yọ̀, kí inú yín máa dùn, nítorí èrè yín pọ̀ ní ọ̀run. Nítorí bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe inúnibíni sí àwọn wolii tí ó ti wà ṣiwaju yín. “Ẹ̀yin ni iyọ̀ ayé; ṣugbọn bí iyọ̀ bá di òbu, kí ni yóo tún sọ ọ́ di iyọ̀ gidi mọ́? Kò wúlò fún ohunkohun mọ́ àfi kí á dà á nù, kí eniyan máa tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀. “Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ìlú tí a tẹ̀dó sórí òkè, kò ṣe é gbé pamọ́. Wọn kì í tan fìtílà tán kí wọ́n fi igbá bò ó; lórí ọ̀pá fìtílà ni wọ́n ń gbé e kà. Yóo wá fi ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo ẹni tí ó wà ninu ilé. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ìmọ́lẹ̀ yín níláti máa tàn níwájú àwọn eniyan, kí wọn lè rí iṣẹ́ rere yín, kí wọn lè máa yin Baba yín tí ó ń bẹ lọ́run lógo. “Ẹ má ṣe rò pé mo wá pa Òfin Mose ati ọ̀rọ̀ àwọn wolii run ni. N kò wá láti pa wọ́n run; mo wá láti mú wọn ṣẹ ni. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, títí ọ̀run ati ayé yóo fi kọjá, kínńkínní, tabi ẹyọ ọ̀rọ̀ kan ninu òfin, kò ní yẹ̀ títí gbogbo rẹ̀ yóo fi ṣẹ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá rú èyí tí ó kéré jùlọ ninu àwọn òfin wọnyi, tí ó sì tún ń kọ́ àwọn eniyan láti máa ṣe bẹ́ẹ̀, òun ni yóo di ẹni ìkẹyìn patapata ní ìjọba ọ̀run. Ṣugbọn ẹni tí ó bá ń pa àwọn àṣẹ wọnyi mọ́, tí ó tún ń kọ́ àwọn eniyan láti máa ṣe bẹ́ẹ̀, òun ni yóo di aṣiwaju ní ìjọba ọ̀run. Nítorí mo wí fun yín pé bí òdodo yín kò bá tayọ ti àwọn amòfin ati ti àwọn Farisi, ẹ kò ní wọ ìjọba ọ̀run. “Ẹ ti gbọ́ tí a ti sọ fún àwọn baba-ńlá wa pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ pa eniyan; ẹni tí ó bá pa eniyan yóo bọ́ sinu ẹjọ́.’ Ṣugbọn èmi wá ń sọ fún yín pé, ẹni tí ó bá bínú sí arakunrin rẹ̀ yóo bọ́ sinu ẹjọ́. Ẹni tí ó bá bú arakunrin rẹ̀, yóo jẹ́jọ́ níwájú àwọn ìgbìmọ̀ ìlú. Ẹni tí ó bá sọ fún arakunrin rẹ̀ pé, ‘Ìwọ òmùgọ̀ yìí’ yóo wà ninu ewu iná ọ̀run àpáàdì. Nítorí náà bí o bá fẹ́ mú ọrẹ wá sórí pẹpẹ ìrúbọ, tí o wá ranti pé arakunrin rẹ ní ọ sinu, fi ọrẹ rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ ìrúbọ, kí o kọ́kọ́ lọ bá arakunrin rẹ, kí ẹ parí ìjà tí ó wà ní ààrin yín ná. Lẹ́yìn náà kí o pada wá rú ẹbọ rẹ. “Tètè bá ẹni tí ó pè ọ́ lẹ́jọ́ rẹ́ nígbà tí ẹ bá jọ ń lọ sí ilé ẹjọ́. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, yóo fà ọ́ fún onídàájọ́. Onídàájọ́ yóo fà ọ́ fún ọlọ́pàá, ọlọ́pàá yóo bá gbé ọ jù sẹ́wọ̀n. Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, ìwọ kò ní jáde kúrò níbẹ̀ títí ìwọ yóo fi san gbogbo gbèsè rẹ láìku kọbọ. “Ẹ ti gbọ́ tí a ti sọ fún àwọn baba ńlá wa pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè.’ Ṣugbọn èmi wá ń sọ fun yín pé ẹnikẹ́ni tí ó bá wo obinrin pẹlu èrò láti bá a lòpọ̀, ó ti ṣe àgbèrè pẹlu rẹ̀ ná ní ọkàn rẹ̀. Bí ojú ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ sọnù. Ó sàn fún ọ pé kí ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀yà ara rẹ kí ó ṣègbé jù pé kí á sọ gbogbo ara rẹ sí ọ̀run àpáàdì lọ. Bí ọwọ́ ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù. Ó sàn fún ọ kí ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀yà ara rẹ ó ṣègbé jù kí gbogbo ara rẹ lọ sí ọ̀run àpáàdì lọ. “Wọ́n sọ pé, ‘Ẹni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ níláti fún un ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀.’ Ṣugbọn èmi wá ń sọ fun yín pé ẹni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, láìjẹ́ pé aya yìí ṣe ìṣekúṣe, ó mú un ṣe àgbèrè. Ẹni tí ó bá sì fẹ́ obinrin tí a kọ̀ sílẹ̀, òun náà ṣe àgbèrè. “Ẹ ti tún gbọ́ tí a sọ fún àwọn baba-ńlá wa pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fi ìbúra jẹ́jẹ̀ẹ́ láì mú un ṣẹ. O gbọdọ̀ san ẹ̀jẹ́ tí o bá jẹ́ fún Oluwa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.’ Ṣugbọn èmi wá ń sọ fun yín pé, ẹ má ṣe búra rárá; ìbáà ṣe pé kí ẹ fi ọ̀run búra, nítorí ìtẹ́ Ọlọrun ni; tabi pé kí ẹ fi ayé búra, nítorí ìtìsẹ̀ tí Ọlọrun gbé ẹsẹ̀ lé ni. Ẹ má fi Jerusalẹmu búra, nítorí ìlú ọba tí ó tóbi ni; tabi pé kí ẹ fi orí yín búra, nítorí ẹ kò lè dá ẹyọ irun kan níbẹ̀, ìbáà ṣe funfun tabi dúdú. Ṣugbọn kí ‘Bẹ́ẹ̀ ni’ yín jẹ́ ‘Bẹ́ẹ̀ ni,’ kí ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́’ yín sì jẹ́ ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́.’ Ohun tí ẹ bá sọ yàtọ̀ sí èyí, ọ̀rọ̀ ẹni-ibi nì ni. “Ẹ ti gbọ́ tí a sọ pé, ‘Nígbà tí o bá fẹ́ gbẹ̀san, ojú dípò ojú ati eyín dípò eyín ni.’ Ṣugbọn èmi wá ń sọ fún yín pé, ẹ má ṣe gbẹ̀san bí ẹnikẹ́ni bá ṣe yín níbi. Kàkà bẹ́ẹ̀, bí ẹnìkan bá gbá yín létí ọ̀tún, ẹ kọ ti òsì sí i. Ẹni tí ó bá fẹ́ pè ọ́ lẹ́jọ́ láti gba àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ, jẹ́ kí ó gba ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ náà. Bí ẹnìkan bá fi agbára mú ọ pé kí o ru ẹrù òun dé ibùsọ̀ kan, bá a rù ú dé ibùsọ̀ keji. Ẹni tí ó bá bèèrè nǹkan lọ́wọ́ rẹ, fi fún un. Má ṣe kọ̀ fún ẹni tí ó bá fẹ́ yá nǹkan lọ́wọ́ rẹ. “Ẹ ti gbọ́ tí a ti sọ pé, ‘Fẹ́ràn aládùúgbò rẹ, kí o kórìíra ọ̀tá rẹ.’ Ṣugbọn èmi wá ń sọ fun yín pé, ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín. Ẹ máa gbadura fún àwọn tí ó ṣe inúnibíni yín. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ti di ọmọ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run. Nítorí a máa mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn eniyan burúkú ati àwọn eniyan rere; a sì máa rọ òjò sórí àwọn olódodo ati sórí àwọn alaiṣododo. Nítorí bí ẹ bá fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn yín, èrè wo ni ó wà níbẹ̀? Mo ṣebí àwọn agbowó-odè náà a máa ṣe bẹ́ẹ̀. Tí ẹ bá ń kí àwọn arakunrin yín nìkan, kí ni ẹ ṣe ju àwọn ẹlòmíràn lọ? Mo ṣebí àwọn abọ̀rìṣà náà ń ṣe bẹ́ẹ̀! Nítorí náà, bí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ti pé ninu ìṣe rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ̀yin náà pé. “Ẹ ṣọ́ra nígbà tí ẹ bá ń ṣe iṣẹ́ ẹ̀sìn yín, ẹ má máa hùwà ṣe-á-rí-mi, kí àwọn eniyan baà lè rí ohun tí ẹ̀ ń ṣe. Bí ẹ bá ń hùwà ṣe-á-rí-mi, ẹ kò ní èrè lọ́dọ̀ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run. “Nítorí náà, nígbà tí o bá ń ṣe ìtọrẹ àánú, má ṣe gbé agogo síta gẹ́gẹ́ bí àwọn aláṣehàn tí ń ṣe ninu àwọn ilé ìpàdé ati ní ojú títì ní ìgboro, kí wọn lè gba ìyìn eniyan. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, wọ́n ti gba èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Ṣugbọn nígbà tí o bá ń ṣe ìtọrẹ àánú, má tilẹ̀ jẹ́ kí ọwọ́ òsì rẹ mọ ohun tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ń ṣe; kí ìtọrẹ àánú rẹ jẹ́ ohun ìkọ̀kọ̀. Baba rẹ, tí ó rí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀ yóo sì san ẹ̀san rẹ fún ọ. “Nígbà tí ẹ bá ń gbadura, ẹ má ṣe bí àwọn aláṣehàn. Nítorí wọ́n fẹ́ràn kí wọ́n máa dúró gbadura ninu ilé ìpàdé ati ní ẹ̀bá títì, kí àwọn eniyan lè rí wọn. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, wọ́n ti gba èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Ṣugbọn nígbà tí ìwọ bá ń gbadura, wọ inú yàrá rẹ lọ, ti ìlẹ̀kùn rẹ, kí o gbadura sí Baba rẹ tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀. Baba rẹ, tí ó rí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀, yóo san ẹ̀san rẹ fún ọ. “Nígbà tí ẹ bá ń gbadura, ẹ má máa wí nǹkankan náà títí, bí àwọn abọ̀rìṣà ti ń ṣe. Nítorí wọ́n rò pé nípa ọ̀rọ̀ pupọ ni adura wọn yóo ṣe gbà. Ẹ má ṣe fara wé wọn, nítorí Baba yín ti mọ ohun tí ẹ nílò kí ẹ tó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Nítorí náà, báyìí ni kí ẹ̀yin máa gbadura: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run: Kí á bọ̀wọ̀ fún orúkọ mímọ́ rẹ, kí ìjọba rẹ dé, ìfẹ́ tìrẹ ni kí á ṣe ní ayé bí wọ́n ti ń ṣe ní ọ̀run. Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí. Dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá gẹ́gẹ́ bí àwa náà ti dárí ji àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ wá. Má fà wá sinu ìdánwò, ṣugbọn gbà wá lọ́wọ́ èṣù.’ “Nítorí bí ẹ bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan jì wọ́n, Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóo dáríjì yín. Ṣugbọn bí ẹ kò bá dáríjì àwọn eniyan, Baba yín kò ní dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín. “Nígbà tí ẹ bá ń gbààwẹ̀, ẹ má máa ṣe bí àwọn aláṣehàn tí wọ́n máa ń fajúro, kí àwọn eniyan lè rí i lójú wọn pé wọ́n ń gbààwẹ̀. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, wọ́n ti gba èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Ṣugbọn nígbà tí ìwọ bá ń gbààwẹ̀, bọ́jú kí o sì fi nǹkan pa ara, kí ó má baà hàn sí àwọn eniyan pé ò ń gbààwẹ̀, àfi sí Baba rẹ tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀. Baba rẹ, tí ó rí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀, yóo san ẹ̀san fún ọ. “Ẹ má ṣe kó ìṣúra jọ fún ara yín ní ayé, níbi tí kòkòrò lè bà á jẹ́, tí ó sì lè dógùn-ún. Àwọn olè tún lè wá a kàn kí wọ́n jí i lọ. Ṣugbọn ẹ kó ìṣúra jọ fún ara yín ní ọ̀run, níbi tí kòkòrò kò lè bà á jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kò lè dógùn-ún, àwọn olè kò sì lè wá a kàn kí wọ́n jí i lọ níbẹ̀. Nítorí níbi tí ìṣúra rẹ bá wà, níbẹ̀ náà ni ọkàn rẹ yóo wà. “Ojú ni ìmọ́lẹ̀ ara. Bí ojú rẹ bá ríran kedere, gbogbo ara rẹ yóo ní ìmọ́lẹ̀. Ṣugbọn bí ojú rẹ kò bá ríran tààrà, gbogbo ara rẹ ni yóo ṣókùnkùn. Bí ìmọ́lẹ̀ tí ó wà ninu rẹ bá wá di òkùnkùn, báwo ni òkùnkùn náà yóo ti pọ̀ tó! “Kò sí ẹni tí ó lè sin oluwa meji. Nítorí ọ̀kan ni yóo ṣe: ninu kí ó kórìíra ọ̀kan, kí ó fẹ́ràn ekeji, tabi kí ó fara mọ́ ọ̀kan, kí ó má ka ekeji sí. Ẹ kò lè sin Ọlọrun, kí ẹ tún máa bọ owó. “Nítorí èyí ni mo ṣe sọ fun yín pé kí ẹ má máa ṣe àníyàn nípa ẹ̀mí yín, pé kí ni ẹ óo jẹ tabi kí ni ẹ óo mu, tabi pé kí ni ẹ óo fi bora. Mo ṣebí ẹ̀mí yín ju oúnjẹ lọ; ati pé ara yín ju aṣọ lọ. Ẹ wo àwọn ẹyẹ lójú ọ̀run. Wọn kì í fúnrúgbìn, wọn kì í kórè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kó nǹkan oko jọ sinu abà. Sibẹ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ń bọ́ wọn. Mo ṣebí ẹ̀yin sàn ju àwọn ẹyẹ lọ! Ta ni ninu yín tí ó lè ṣe àníyàn títí tí ó lè fi kún ọjọ́ ayé rẹ̀? “Kí ní ṣe tí ẹ̀ ń ṣe àníyàn nípa ohun tí ẹ óo wọ̀? Ẹ ṣe akiyesi àwọn òdòdó inú igbó bí wọ́n ti ń dàgbà. Wọn kì í ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í rànwú. Sibẹ mo sọ fun yín pé Solomoni pàápàá ninu gbogbo ìgúnwà rẹ̀ kò lè wọ aṣọ tí ó lẹ́wà bíi ti ọ̀kan ninu àwọn òdòdó yìí. Ǹjẹ́ bí Ọlọrun bá wọ koríko ìgbẹ́ láṣọ báyìí, koríko tí yóo wà lónìí, tí a óo fi dáná lọ́la, mélòó-mélòó ni yóo wọ̀ yín láṣọ, ẹ̀yin onigbagbọ kékeré? “Nítorí náà, ẹ má ṣe àníyàn pé kí ni ẹ óo jẹ? Tabi, kí ni ẹ óo mu? Tabi kí ni ẹ óo fi bora? Nítorí gbogbo nǹkan wọnyi ni àwọn abọ̀rìṣà ń lépa. Nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo wọn. Ṣugbọn ẹ kọ́kọ́ máa wá ìjọba Ọlọrun ná ati òdodo rẹ̀, gbogbo nǹkan wọnyi ni a óo fi kún un fún yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe àníyàn nípa nǹkan ti ọ̀la; nítorí ọ̀la ni nǹkan ti ọ̀la wà fún; wahala ti òní nìkan ti tó fún òní láì fi ti ọ̀la kún un. “Ẹ má ṣe dá eniyan lẹ́jọ́, kí Ọlọrun má baà dá ẹ̀yin náà lẹ́jọ́. Nítorí irú ẹjọ́ tí ẹ bá dá eniyan ni Ọlọrun yóo dá ẹ̀yin náà. Irú ìwọ̀n tí ẹ bá lò fún eniyan ni Ọlọrun yóo lò fún ẹ̀yin náà. Kí ló dé tí o fi ń wo ẹ̀ẹ́rún igi tí ó wà lójú arakunrin rẹ, nígbà tí o kò ṣe akiyesi ìtì igi tí ó wà lójú ìwọ alára? Tabi báwo ni o ṣe lè wí fún arakunrin rẹ pé, ‘Jẹ́ kí ń bá ọ yọ ẹ̀ẹ́rún igi tí ó wà lójú rẹ,’ nígbà tí ó jẹ́ pé ìtì igi wà ní ojú tìrẹ alára? Ìwọ a-rí-tẹni-mọ̀-ọ́n-wí, kọ́kọ́ yọ ìtì igi tí ó wà lójú rẹ kúrò; nígbà náà o óo ríran kedere láti lè yọ ẹ̀ẹ́rún igi tí ó wà lójú arakunrin rẹ. “Ẹ má ṣe fi nǹkan mímọ́ fún ajá, ẹ má sì ṣe fi ìlẹ̀kẹ̀ iyebíye yín siwaju ẹlẹ́dẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn yóo fi ẹsẹ̀ tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀, wọn yóo sì pada bù yín jẹ! “Ẹ bèèrè, a óo sì fi fun yín. Ẹ wá kiri, ẹ óo sì rí. Ẹ kanlẹ̀kùn, a óo sì ṣí i fun yín. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá bèèrè ni ó ń rí gbà; ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wá nǹkan kiri ni ó ń rí i; ẹnikẹ́ni tí ó bá ń kanlẹ̀kùn ni à ń ṣí i sílẹ̀ fún. Ta ni ninu yín, tí ọmọ rẹ̀ bá bèèrè àkàrà, tí ó jẹ́ fún un ní òkúta? Tabi tí ó bà bèèrè ẹja, tí ó jẹ́ fún un ní ejò? Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin tí ẹ burú báyìí bá mọ̀ bí a tií fi ohun tí ó dára fún ọmọ yín, mélòó-mélòó ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóo fi ohun rere fún àwọn tí ó bá bèèrè lọ́dọ̀ rẹ̀. “Nítorí náà, gbogbo bí ẹ bá ti fẹ́ kí eniyan ṣe si yín, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ̀yin náà ṣe sí wọn. Kókó Òfin ati ọ̀rọ̀ àwọn wolii nìyí. “Ẹ gba ẹnu ọ̀nà tí ó fún wọlé. Ọ̀nà ọ̀run àpáàdì gbòòrò, ẹnu ọ̀nà rẹ̀ sì fẹ̀. Ọ̀pọ̀ eniyan ni ó ń gba ibẹ̀. Ṣugbọn ọ̀nà ìyè há, ẹnu ọ̀nà rẹ̀ sì fún. Díẹ̀ sì ni àwọn tí wọ́n rí i. “Ẹ ṣọ́ra fún àwọn wolii èké tí wọn máa ń wá sọ́dọ̀ yín. Ní òde, wọ́n dàbí aguntan, ṣugbọn ninu, ìkookò tí ó ya ẹhànnà ni wọ́n. Nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn ni ẹ óo fi mọ̀ wọ́n. Kò sí ẹni tí ó lè ká èso àjàrà lórí igi ẹ̀wọ̀n agogo tabi kí ó rí èso ọ̀pọ̀tọ́ lórí igi ẹ̀gún ọ̀gàn. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni: gbogbo igi tí ó bá dára a máa so èso tí ó dára; igi tí kò bá dára a máa so èso burúkú. Igi tí ó bá dára kò lè so èso burúkú; bẹ́ẹ̀ ni igi burúkú kò lè so èso rere. Igikígi tí kò bá so èso rere, gígé ni a óo gé e lulẹ̀, tí a óo sì fi dáná. Nítorí náà nípa èso wọn ni ẹ óo fi mọ̀ wọ́n. “Kì í ṣe gbogbo àwọn tí ń pè mí ní, ‘Oluwa, Oluwa’ ni yóo wọ ìjọba ọ̀run, bíkòṣe àwọn tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ó ń bẹ ní ọ̀run. Ọ̀pọ̀ eniyan ni yóo wí fún mi ní ọjọ́ ìdájọ́ pé, ‘Oluwa, Oluwa, a kéde ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní orúkọ rẹ; a lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde ní orúkọ rẹ; a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu ní orúkọ rẹ.’ Ṣugbọn n óo wí fún wọn pé, ‘Èmi kò mọ̀ yín rí. Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin oníṣẹ́ ibi wọnyi!’ “Nítorí náà, gbogbo ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi yìí, tí ó bá fi ṣe ìwà hù dàbí ọlọ́gbọ́n eniyan kan, tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí àpáta. Òjò rọ̀; àgbàrá dé, ẹ̀fúùfù sì kọlu ilé náà; ṣugbọn kò wó, nítorí ìpìlẹ̀ rẹ̀ wà lórí àpáta. “Ṣugbọn ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi yìí, tí kò bá fi ṣe ìwà hù, ó dàbí òmùgọ̀ eniyan kan tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí iyanrìn. Òjò rọ̀, àgbàrá dé, ẹ̀fúùfù sì kọlu ilé náà. Ó bá wó! Wíwó rẹ̀ sì bani lẹ́rù lọpọlọpọ.” Nígbà tí Jesu parí àwọn ọ̀rọ̀ wọnyi, ẹnu ya àwọn eniyan sí ẹ̀kọ́ rẹ̀; nítorí ó ń kọ́ wọn bí ẹni tí ó ní àṣẹ, kì í ṣe bí àwọn amòfin wọn. Nígbà tí Jesu sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, ọ̀pọ̀ àwọn eniyan ń tẹ̀lé e. Ẹnìkan tí ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀ sì wá, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Alàgbà bí o bá fẹ́, o lè sọ ara mi di mímọ́.” Jesu bá na ọwọ́ rẹ̀, ó fi kàn án, ó ní, “Mo fẹ́, kí ara rẹ di mímọ́.” Lẹsẹkẹsẹ ni àrùn ẹ̀tẹ̀ náà bá kúrò lára rẹ̀. Jesu wá sọ fún un pé, “Má sọ fún ẹnikẹ́ni. Ṣugbọn, lọ, fi ara rẹ han alufaa, kí o ṣe ìrúbọ gẹ́gẹ́ bí Mose ti pa á láṣẹ, bí ẹ̀rí fún wọn pé ara rẹ ti dá.” Nígbà tí Jesu wọ ìlú Kapanaumu, ọ̀gágun kan tí ó ní ọgọrun-un ọmọ-ogun lábẹ́ rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, ó ń bẹ̀ ẹ́; ó ní, “Alàgbà, ọmọ-ọ̀dọ̀ mi kan wà ninu ilé tí àrùn ẹ̀gbà ń dà láàmú, ó sì ń joró gidigidi.” Jesu bá sọ fún un pé, “N óo wá, n óo sì wò ó sàn.” Ṣugbọn ọ̀gágun náà dáhùn pé, “Alàgbà, èmi kò yẹ ní ẹni tí ìwọ ìbá wọ inú ilé rẹ̀. Ṣá sọ gbolohun kan, ara ọmọ-ọ̀dọ̀ mi yóo sì dá. Nítorí ẹni tí ó wà lábẹ́ àṣẹ ni èmi náà, mo ní àwọn ọmọ-ogun lábẹ́ mi. Bí mo bá sọ fún ọ̀kan pé, ‘Lọ!’ yóo lọ ni. Bí mo bá sọ fún òmíràn pé, ‘Wá!’ yóo sì wá. Bí mo bá sọ fún ẹrú mi pé, ‘Ṣe èyí!’ yóo ṣe é ni.” Nígbà tí Jesu gbọ́, ẹnu yà á, ó sọ fún àwọn tí ó ń tẹ̀lé e pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, n kò rí irú igbagbọ báyìí ní Israẹli pàápàá! Mo tún ń sọ fun yín pé, ọpọlọpọ eniyan yóo wá láti ìlà oòrùn ati láti ìwọ̀ oòrùn, wọn yóo bá Abrahamu ati Isaaki ati Jakọbu jẹun ní ìjọba ọ̀run. Ṣugbọn àwọn ọmọ ìjọba ọ̀run ni a óo tì jáde sinu òkùnkùn biribiri, níbi tí ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà.” Jesu bá sọ fún ọ̀gágun náà pé, “Máa lọ, gẹ́gẹ́ bí o ti gbàgbọ́, bẹ́ẹ̀ ni kí ó rí fún ọ.” Ara ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ sì dá ní àkókò náà gan-an. Nígbà tí Jesu wọ inú ilé Peteru, ó rí ìyá iyawo Peteru tí ibà dá dùbúlẹ̀. Jesu bá fi ọwọ́ kàn án lọ́wọ́, ibà náà sì fi í sílẹ̀. Ó bá dìde, ó bá tọ́jú oúnjẹ fún un. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, wọ́n gbé ọpọlọpọ eniyan tí wọ́n ní ẹ̀mí èṣù wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ọ̀rọ̀ ẹnu ni ó fi lé àwọn ẹ̀mí náà jáde, ó sì tún wo gbogbo àwọn tí ara wọn kò dá sàn. Báyìí ni ọ̀rọ̀ tí wolii Aisaya sọ ṣẹ, nígbà tí ó sọ pé, “Òun fúnra rẹ̀ ni ó mú àìlera wa lọ, ó sì gba àìsàn wa fún wa.” Nígbà tí Jesu rí ọ̀pọ̀ eniyan tí wọ́n yí i ká, ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọn kọjá sí òdìkejì òkun. Amòfin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sọ fún un pé, “Olùkọ́ni, mo fẹ́ máa tẹ̀lé ọ níbikíbi tí o bá ń lọ.” Jesu wí fún un pé, “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ìtẹ́; ṣugbọn Ọmọ-Eniyan kò ní ibi tí yóo gbé orí rẹ̀ lé.” Ẹlòmíràn ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Alàgbà, jẹ́ kí n kọ́ lọ sìnkú baba mi.” Ṣugbọn Jesu sọ fún un pé, “Ìwọ tẹ̀lé mi, jẹ́ kí àwọn òkú máa sin òkú ara wọn.” Jesu wọ ọkọ̀ ojú omi kan, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Ìgbì líle kan sì dé lójú omi òkun; ó pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé omi fẹ́rẹ̀ bo ọkọ̀; ṣugbọn Jesu sùnlọ. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá lọ jí i; wọ́n ní, “Oluwa, gbà wá là, à ń ṣègbé lọ!” Ó bá sọ fún wọn pé, “Ẹ ti ṣe lójo bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin onigbagbọ kékeré wọnyi?” Ó bá dìde, ó bá afẹ́fẹ́ ati òkun wí, ìdákẹ́rọ́rọ́ ńlá bá dé. Ẹnu ya àwọn eniyan náà. Wọ́n ní, “Irú eniyan wo ni èyí, tí afẹ́fẹ́ ati òkun ń gbọ́ràn sí i lẹ́nu?” Nígbà tí ó dé òdìkejì òkun, ní ilẹ̀ àwọn ará Gadara, àwọn ọkunrin meji tí wọn ní ẹ̀mí èṣù jáde láti inú itẹ́ òkú, wọ́n wá pàdé rẹ̀. Wọ́n le tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé kò sí ẹni tí ó lè gba ọ̀nà ibẹ̀ kọjá. Wọ́n bá kígbe pé, “Kí ni ó pa tàwa-tìrẹ pọ̀, ìwọ Ọmọ Ọlọrun? Ṣé o dé láti wá dà wá láàmú ṣáájú àkókò wa ni?” Agbo ọpọlọpọ ẹlẹ́dẹ̀ kan wà tí wọn ń jẹ lókèèrè. Àwọn ẹ̀mí èṣù náà bá bẹ Jesu pé, “Bí o óo bá lé wa jáde, lé wa lọ sinu agbo ẹlẹ́dẹ̀ ọ̀hún nnì.” Jesu bá wí fún wọn pé, “Ẹ lọ!” Wọ́n bá jáde lọ sí inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀. Gbogbo agbo ẹlẹ́dẹ̀ bá dorí kọ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè náà, wọ́n sáré lọ, wọ́n sì rì sómi. Àwọn tí wọn ń tọ́jú agbo ẹlẹ́dẹ̀ bá sá kúrò níbẹ̀, wọ́n lọ sí ààrin ìlú, wọ́n lọ ròyìn gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ati ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí ó ní ẹ̀mí èṣù. Gbogbo ìlú bá jáde lọ pàdé Jesu. Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé kí ó jọ̀wọ́ kí ó kúrò ní agbègbè wọn. Jesu wọ inú ọkọ̀, ó rékọjá sí òdìkejì òkun, ó bá dé ìlú ara rẹ̀. Àwọn kan bá gbé arọ kan wá, ó dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn. Nígbà tí Jesu rí igbagbọ wọn, ó sọ fún arọ náà pé, “Ṣe ara gírí, ọmọ, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.” Àwọn amòfin kan ń rò ninu ara wọn pé, “Ọkunrin yìí ń sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun.” Ṣugbọn Jesu mọ èrò inú wọn; ó bá bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń ro èrò burúkú ninu ọkàn yín? Èwo ni ó rọrùn jù, láti sọ pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ ni,’ tabi láti sọ pé, ‘Dìde, kí o máa rìn?’ Ṣugbọn kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ-Eniyan ní àṣẹ ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan ni.” Nígbà náà ni ó wá wí fún arọ náà pé “Dìde, gbé ibùsùn rẹ, máa lọ sí ilé rẹ.” Arọ náà bá dìde, ó lọ sí ilé rẹ̀. Ẹ̀rù ba àwọn eniyan tí wọn ń wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Wọ́n fi ògo fún Ọlọrun tí ó fi irú àṣẹ bẹ́ẹ̀ fún eniyan. Nígbà tí Jesu kúrò níbẹ̀, ó rí ọkunrin kan tí ó ń jẹ́ Matiu tí ó jókòó níbi tí ó ti ń gba owó-odè. Ó wí fún un pé, “Máa tẹ̀lé mi.” Kíá, ó bá dìde, ó ń tẹ̀lé e. Matiu se àsè ní ilé rẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wọ́n wá, tí wọn ń bá Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jẹun. Nígbà tí àwọn Farisi rí i, wọ́n bi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Kí ní ṣe tí olùkọ́ yín fi ń bá àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun?” Nígbà tí Jesu gbọ́, ó ní, “Àwọn tí ara wọn le kò nílò oníṣègùn bíkòṣe àwọn tí ara wọn kò dá. Ẹ lọ kọ́ ìtumọ̀ gbolohun yìí: Ọlọrun sọ pé, ‘Àánú ṣíṣe ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ rírú.’ Nítorí náà kì í ṣe àwọn olódodo ni mo wá pè, bíkòṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.” Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, “Kí ló dé tí àwa ati àwọn Farisi ń gbààwẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kì í gbààwẹ̀?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ iyawo kò lè máa ṣọ̀fọ̀ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ iyawo bá wà lọ́dọ̀ wọn. Àkókò ń bọ̀ nígbà tí a óo gba ọkọ iyawo lọ́wọ́ wọn; wọn yóo máa gbààwẹ̀ nígbà náà. “Kò sí ẹni tíí fi ìrépé aṣọ titun tí kò ì tíì wọ omi rí lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù, Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìrépé aṣọ titun náà yóo súnkì lára ògbólógbòó ẹ̀wù náà, yíya rẹ̀ yóo wá burú ju ti àkọ́kọ́ lọ. Kò sí ẹni tíí fi ọtí titun sinu ògbólógbòó àpò awọ. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ògbólógbòó àpò awọ náà yóo bẹ́; ati ọtí ati àpò yóo sì ṣòfò. Ṣugbọn ninu àpò awọ titun ni à ń fi ọtí titun sí, ati ọtí ati àpò yóo wà ní ìpamọ́.” Bí Jesu tí ń sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn, ìjòyè kan wá, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Ọmọdebinrin mi ṣẹ̀ṣẹ̀ kú nisinsinyii ni, ṣugbọn wá gbé ọwọ́ rẹ lé e, yóo sì yè.” Jesu bá dìde. Ó ń tẹ̀lé e lọ pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Obinrin kan wà, tí nǹkan oṣù rẹ̀ kò tètè dá rí fún ọdún mejila, ó gba ẹ̀yìn wá, ó fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ Jesu; nítorí ó ń sọ ninu ọkàn rẹ̀ pé, “Bí mo bá sá ti lè fi ọwọ́ kan etí aṣọ rẹ̀, ara mi yóo dá.” Jesu bá yipada, ó rí obinrin náà, ó ní, “Ṣe ara gírí, ọmọbinrin. Igbagbọ rẹ ti mú ọ lára dá.” Ara obinrin náà bá dá láti àkókò náà lọ. Nígbà tí Jesu dé ilé ìjòyè náà, ó rí àwọn tí wọn ń fun fèrè ati ọ̀pọ̀ eniyan tí wọn ń ké. Ó ní, “Ẹ sún sẹ́yìn, nítorí ọmọde náà kò kú, ó ń sùn ni.” Wọ́n bá ń fi í ṣe ẹlẹ́yà. Lẹ́yìn tí ó ti lé àwọn eniyan jáde, ó wọ inú ilé, ó mú ọmọbinrin náà lọ́wọ́, ọmọbinrin náà bá dìde. Òkìkí rẹ̀ kàn ká gbogbo agbègbè náà. Nígbà tí Jesu kúrò níbẹ̀, àwọn afọ́jú meji kan tẹ̀lé e, wọ́n ń kígbe pé, “Ọmọ Dafidi, ṣàánú wa.” Nígbà tí ó wọ inú ilé, àwọn afọ́jú náà tọ̀ ọ́ lọ. Jesu bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ gbàgbọ́ pé mo lè wò yín sàn?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa.” Ó bá fi ọwọ́ kàn wọ́n lójú, ó ní, “Kí ó rí fun yín gẹ́gẹ́ bí igbagbọ yín.” Ojú wọn bá là. Jesu wá kìlọ̀ fún wọn gidigidi, ó ní “Ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀.” Ṣugbọn nígbà tí wọ́n jáde, ńṣe ni wọ́n ń pòkìkí rẹ̀ káàkiri gbogbo agbègbè náà. Bí àwọn afọ́jú náà ti jáde, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kan mú ọkunrin kan, tí ẹ̀mí èṣù mú kí ó yadi, wá sọ́dọ̀ Jesu. Ṣugbọn bí ó ti lé ẹ̀mí èṣù náà jáde ni odi náà bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀. Ẹnu ya gbogbo àwọn eniyan, wọ́n ń sọ pé, “A kò rí irú èyí rí ní Israẹli.” Ṣugbọn àwọn Farisi ń sọ pé, “Agbára olórí àwọn ẹ̀mí èṣù ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.” Jesu ń rìn kiri ní gbogbo àwọn ìlú ati àwọn ìletò, ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu àwọn ilé ìpàdé, ó ń waasu ìyìn rere ìjọba Ọlọrun, ó sì ń wo oríṣìíríṣìí àrùn ati àìlera sàn. Nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ eniyan náà, àánú wọn ṣe é nítorí wọ́n dàbí aguntan tí kò ní olùṣọ́, tí ọkàn wọn dààmú, tí ó sì rẹ̀wẹ̀sì. Ó bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Àwọn ohun tí ó tó kórè pọ̀, ninu oko, ṣugbọn àwọn òṣìṣẹ́ kò pọ̀. Nítorí náà ẹ bẹ Oluwa ìkórè kí ó rán àwọn òṣìṣẹ́ sí ibi ìkórè rẹ̀.” Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mejila sọ́dọ̀, ó fún wọn ní àṣẹ láti máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ati láti máa ṣe ìwòsàn oríṣìíríṣìí àrùn ati àìsàn. Orúkọ àwọn aposteli mejila náà nìwọ̀nyí: Simoni tí ó tún ń jẹ́ Peteru, ati Anderu arakunrin rẹ̀; lẹ́yìn náà Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin rẹ̀. Filipi ati Batolomiu, Tomasi ati Matiu agbowó-odè, Jakọbu ọmọ Alfeu ati Tadiu. Simoni ará Kenaani ati Judasi Iskariotu, ẹni tí ó fi Jesu fún àwọn ọ̀tá rẹ̀. Àwọn mejila yìí ni Jesu rán níṣẹ́, ó pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ má gba ọ̀nà ìlú àwọn tí kì í ṣe Juu lọ; bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má wọ ìlú àwọn ará Samaria. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ tọ àwọn aguntan ilé Israẹli tí ó sọnù lọ. Bí ẹ ti ń lọ, ẹ máa waasu pé, ‘Ìjọba ọ̀run súnmọ́ tòsí!’ Ẹ máa wo aláìsàn sàn; ẹ máa jí àwọn òkú dìde; ẹ máa sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́; ẹ máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ọ̀fẹ́ ni ẹ rí agbára wọnyi gbà. Ọ̀fẹ́ ni kí ẹ máa lò wọ́n. Ẹ má fi owó wúrà tabi fadaka tabi idẹ sinu àpò yín. Ẹ má mú àpò tí wọ́n fi ń ṣagbe lọ́wọ́ lọ. Ẹ má mú ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ meji. Ẹ má wọ bàtà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má mú ọ̀pá lọ́wọ́. Oúnjẹ òṣìṣẹ́ tọ́ sí i. “Bí ẹ bá dé ìlú tabi ìletò kan, ẹ fẹ̀sọ̀ wádìí bí ẹni tí ó yẹ kan bá wà níbẹ̀; lọ́dọ̀ rẹ̀ ni kí ẹ máa gbé títí ẹ óo fi kúrò níbẹ̀. Nígbà tí ẹ bá wọ inú ilé kan lọ, ẹ kí wọn pé, ‘Alaafia fún ilé yìí.’ Bí ẹnikẹ́ni tí ó yẹ bá wà ninu ilé náà, kí alaafia tí ẹ ṣe kí ó wà níbẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí alaafia tí ẹ ṣe kí ó pada sọ́dọ̀ yín. Bí ẹnìkan kò bá gbà yín sílé, tabi tí kò bá fetí sí ọ̀rọ̀ yín, ẹ jáde kúrò ninu ilé tabi ìlú náà, kí ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín sílẹ̀. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, yóo sàn fún ilẹ̀ Sodomu ati ti Gomora ní ọjọ́ ìdájọ́, ju ìlú náà lọ! “Ẹ ṣe akiyesi pé mò ń ran yín lọ bí aguntan sáàrin ìkookò. Nítorí náà ẹ gbọ́n bí ejò, kí ẹ sì níwà tútù bí àdàbà. Ẹ kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn eniyan, nítorí wọn yóo fà yín lọ siwaju ìgbìmọ̀ láti fẹ̀sùn kàn yín; wọn yóo nà yín ninu àwọn ilé ìpàdé wọn. Wọn yóo mu yín lọ jẹ́jọ́ níwájú àwọn gomina ati níwájú àwọn ọba nítorí tèmi, kí ẹ lè jẹ́rìí mi níwájú wọn ati níwájú àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Juu. Nígbà tí wọ́n bá mu yín lọ fún ìdájọ́, ẹ má dààmú nípa ohun tí ẹ óo sọ tabi bí ẹ óo ti sọ ọ́; nítorí Ọlọrun yóo fi ohun tí ẹ óo sọ fun yín ní àkókò náà. Nítorí kì í ṣe ẹ̀yin ni yóo máa sọ̀rọ̀, ẹ̀mí Baba yín ni yóo máa sọ̀rọ̀ ninu yín. “Arakunrin yóo fi arakunrin rẹ̀ fún ikú pa; baba yóo fi ọmọ rẹ̀ fún ikú pa. Àwọn ọmọ yóo gbógun ti àwọn òbí wọn, wọn yóo fi wọ́n fún ikú pa. Gbogbo eniyan ni yóo kórìíra yín nítorí orúkọ mi. Ṣugbọn ẹni tí ó bá fara dà á títí dé òpin, òun ni a óo gbà là. Bí wọn bá ṣe inúnibíni yín ní ìlú kan, ẹ sálọ sí ìlú mìíràn. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹ kò ní tíì ya gbogbo ìlú Israẹli tán kí Ọmọ-Eniyan tó dé. “Ọmọ-ẹ̀yìn kò ju olùkọ́ rẹ̀ lọ. Bẹ́ẹ̀ ni ẹrú kò ju oluwa rẹ̀ lọ. Ó tó fún ọmọ-ẹ̀yìn bí ó bá dàbí olùkọ́ rẹ̀. Ó tó fún ẹrú bí ó bá dàbí oluwa rẹ̀. Bí wọ́n bá pe baálé ilé ní Beelisebulu, kí ni wọn yóo pe àwọn ẹni tí ó ń gbé inú ilé rẹ̀! “Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù àwọn eniyan. Kò sí ohun tí ó wà ní ìpamọ́, tí kò ní fara hàn. Kò sì sí ohun àṣírí tí a kò ní mọ̀. Ohun tí mo sọ fun yín níkọ̀kọ̀, ẹ sọ ọ́ ní gbangba. Ohun tí wọ́n yọ́ sọ fun yín, ẹ kéde rẹ̀ lórí òrùlé. Ẹ má bẹ̀rù àwọn tí wọ́n lè pa ara yín, tí wọn kò lè pa ẹ̀mí yín. Ẹni tí ó yẹ kí ẹ bẹ̀rù ni Ọlọrun tí ó lè pa ẹ̀mí ati ara run ní ọ̀run àpáàdì. Ṣebí meji kọbọ ni wọ́n ń ta ológoṣẹ́! Sibẹ ọ̀kan ninu wọn kò lè jábọ́ sílẹ̀ lẹ́yìn Baba yín. Gbogbo irun orí yín ni ó níye. Nítorí náà ẹ má bẹ̀rù; ẹ níye lórí pupọ ju ológoṣẹ́ lọ. “Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú eniyan, èmi náà yóo jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú Baba mi tí ń bẹ lọ́run. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá sẹ́ mi níwájú eniyan, èmi náà yóo sẹ́ ẹ níwájú Baba mi tí ń bẹ lọ́run. “Ẹ má rò pé mo mú alaafia wá sáyé. N kò mú alaafia wá; idà ni mo mú wá. Nítorí mo wá láti dá ìyapa sílẹ̀, láàrin ọmọkunrin ati baba rẹ̀, láàrin ọmọbinrin ati ìyá rẹ̀, ati láàrin iyawo ati ìyá ọkọ rẹ̀. Ará ilé ẹni ni ọ̀tá ẹni. “Ẹni tí ó bá fẹ́ràn baba tabi ìyá rẹ̀ jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ ọkunrin tabi obinrin jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi. Bẹ́ẹ̀ ni, ẹnikẹ́ni tí kò bá gbé agbelebu rẹ̀, kí ó máa tẹ̀lé mi, kò yẹ ní tèmi. Ẹni tí ó bá sì fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là yóo pàdánù rẹ̀; ṣugbọn ẹni tí ó bá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nítorí mi yóo jèrè rẹ̀. “Ẹni tí ó bá gbà yín, èmi ni ó gbà. Ẹni tí ó bá sì gbà mí, ó gba ẹni tí ó fi iṣẹ́ rán mi. Ẹni tí ó bá gba wolii ní orúkọ wolii yóo gba èrè tí ó yẹ wolii. Ẹni tí ó bá gba olódodo ní orúkọ olódodo yóo gba èrè olódodo. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fún ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi yìí tí ó kéré jùlọ ní ife omi tútù mu, nítorí pé ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé kò ní pàdánù èrè rẹ̀.” Lẹ́yìn tí Jesu ti fi gbogbo ìlànà wọnyi lélẹ̀ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mejila tán, ó kúrò níbẹ̀ lọ sí àwọn ìlú wọn, ó ń kọ àwọn eniyan ó sì ń waasu. Johanu gbọ́ ninu ẹ̀wọ̀n nípa iṣẹ́ tí Jesu ń ṣe. Ó bá rán àwọn kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọ́n lọ bi í pé, “Ṣé ìwọ ni ẹni tí ó ń bọ̀ ni, tabi kí á máa retí ẹlòmíràn?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ lọ ròyìn ohun tí ẹ ti gbọ́ ati ohun tí ẹ ti rí fún Johanu. Ẹ sọ fún un pé, àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn arọ ń rìn, ara àwọn adẹ́tẹ̀ ń di mímọ́, àwọn adití ń gbọ́ràn, à ń jí àwọn òkú dìde, a sì ń waasu ìyìn rere fún àwọn talaka. Ẹni tí kò bá ṣiyèméjì nípa mi ṣe oríire!” Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ Johanu pada lọ, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn eniyan nípa Johanu pé, “Kí ni ẹ jáde lọ wò ní aṣálẹ̀? Ṣé koríko tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ síhìn-ín, sọ́hùn-ún? Rárá o! Kí wá ni ẹ jáde lọ wò? Ẹni tí ó wọ aṣọ iyebíye ni bí? Bí ẹ bá ń wá àwọn tí ó wọ aṣọ olówó iyebíye, ẹ lọ sí ààfin ọba! Ṣugbọn kí ni ẹ jáde lọ wò? Wolii ni bí? Bẹ́ẹ̀ ni. Mo sọ fun yín, ó tilẹ̀ ju wolii lọ. Òun ni àkọsílẹ̀ wà nípa rẹ̀ pé: ‘Wò ó! Mo rán oníṣẹ́ mi ṣiwaju rẹ òun ni yóo palẹ̀ mọ́ dè ọ́.’ Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ninu àwọn tí obinrin bí, kò ì tíì sí ẹnìkan tí ó ju Johanu Onítẹ̀bọmi lọ. Sibẹ, ẹni tí ó kéré jù lọ ní ìjọba Ọlọrun jù ú lọ. Láti àkókò tí Johanu Onítẹ̀bọmi ti bẹ̀rẹ̀ sí waasu títí di ìsinsìnyìí ni àwọn alágbára ti gbógun ti ìjọba ọ̀run, wọ́n sì fẹ́ fi ipá gbà á. Nítorí títí di àkókò Johanu gbogbo àwọn wolii ati òfin sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀. Bí ẹ bá fẹ́ gbà á, Johanu ni Elija, tí ó níláti kọ́ wá. Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́. “Kí ni ǹ bá fi ìran yìí wé? Ó dàbí àwọn ọmọde tí wọ́n jókòó ní ọjà, tí wọn ń ké sí àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn pé. ‘A lù fun yín, ẹ kò jó, a pe òkú, ẹ kò ṣọ̀fọ̀.’ Nítorí Johanu dé, kò jẹ, kò mu. Wọ́n ní, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù ni.’ Ọmọ-Eniyan dé, ó ń jẹ, ó ń mu. Wọ́n ní, ‘Ẹ kò rí ọkunrin yìí, oníjẹkújẹ ati ọ̀mùtí, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.’ Ṣugbọn àyọrísí iṣẹ́ Ọlọrun fihàn pé ọgbọ́n rẹ̀ tọ̀nà.” Nígbà náà ni Jesu bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ìlú wọ̀n-ọn-nì wí níbi tí ó ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu pupọ jùlọ, nítorí wọn kò ronupiwada. Ó ní, “O gbé! Korasini. Ìwọ náà sì gbé! Bẹtisaida. Nítorí bí ó bá jẹ́ pé ní Tire ati ní Sidoni ni a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe láàrin yín ni, wọn ìbá ti ronupiwada tipẹ́tipẹ́, tàwọn ti aṣọ ọ̀fọ̀ lára ati eérú lórí. Mo sọ fun yín, yóo sàn fún Tire ati fún Sidoni ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fun yín lọ. Ati ìwọ, Kapanaumu, o rò pé a óo gbé ọ ga dé ọ̀run ni? Rárá o. Ní ọ̀gbun jíjìn ni a óo sọ ọ́ sí! Nítorí bí ó bá jẹ́ pé ní Sodomu ni a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe ninu rẹ ni, ìbá wà títí di òní. Mo sọ fún ọ pé, yóo sàn fún ilẹ̀ Sodomu ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún ọ lọ.” Nígbà náà ni Jesu sọ báyìí pé, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Oluwa ọ̀run ati ayé, nítorí o ti pa nǹkan wọnyi mọ́ fún àwọn ọlọ́gbọ́n ati àwọn olóye, ṣugbọn o fi wọ́n han àwọn òpè. Bẹ́ẹ̀ ni, Baba, nítorí bí ó ti tọ́ ní ojú rẹ ni. “Baba mi ti fi ohun gbogbo lé mi lọ́wọ́. Kò sí ẹni tí ó mọ Ọmọ àfi Baba; bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó mọ Baba, àfi Ọmọ, àtúnfi àwọn tí Ọmọ bá fẹ́ fi Baba hàn fún. “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí ẹrù ìpọ́njú ń wọ̀ lọ́rùn. Èmi yóo fun yín ní ìsinmi. Ẹ gba àjàgà mi sí ọrùn yín, kí ẹ sì wá kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onírẹ̀lẹ̀ ati ọlọ́kàn tútù ni mí, ọkàn yín yóo sì balẹ̀. Nítorí àjàgà mi tuni lára, ẹrù mi sì fúyẹ́.” Ní àkókò náà Jesu ń la oko ọkà kan kọjá ní Ọjọ́ Ìsinmi àwọn Juu. Ebi ń pa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí já ọkà, wọ́n ń jẹ ẹ́. Nígbà tí àwọn Farisi rí i, wọ́n wí fún un pé, “Wò ó! Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ ń ṣe ohun tí kò tọ́ láti ṣe ní Ọjọ́ Ìsinmi.” Ṣugbọn Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ kò kà nípa ohun tí Dafidi ṣe nígbà tí ebi ń pa òun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀? Bí wọ́n ti wọ inú ilé Ọlọrun lọ, tí wọ́n sì jẹ burẹdi tí ó wà lórí tabili níwájú Oluwa, èyí tí ó lòdì sí òfin fún òun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ láti jẹ bíkòṣe fún àwọn alufaa nìkan? Tabi ẹ kò kà ninu ìwé Òfin pé iṣẹ́ àwọn alufaa ninu Tẹmpili ní Ọjọ́ Ìsinmi a máa mú wọn ba Ọjọ́ Ìsinmi jẹ́? Sibẹ wọn kò jẹ̀bi. Mo sọ fun yín pé ẹni tí ó ju Tẹmpili lọ ló wà níhìn-ín yìí. Bí ó bá jẹ́ pé ìtumọ̀ gbolohun yìí ye yín ni, pé: ‘Àánú ṣíṣe ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ rírú’ ẹ kì bá tí dá ẹ̀bi fún aláìṣẹ̀. Nítorí Ọmọ-Eniyan ni Oluwa Ọjọ́ Ìsinmi.” Lẹ́yìn èyí, Jesu kúrò níbẹ̀, ó lọ sí inú ilé ìpàdé wọn. Ọkunrin kan wà níbẹ̀ tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ. Wọ́n bi í pé, “Ṣé ó bá òfin mu láti ṣe ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi?” Kí wọ́n baà lè rí ẹ̀sùn fi kàn án ni wọ́n fi bèèrè ìbéèrè yìí. Ó bá bi wọ́n báyìí pé, “Ta ni ninu yín tí yóo ní aguntan kan, bí ọ̀kan náà bá jìn sí kòtò ní Ọjọ́ Ìsinmi, tí kò ní fà á jáde? Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí eniyan ti sàn ju aguntan lọ, ó tọ́ láti ṣe rere ní Ọjọ́ Ìsinmi.” Ó bá sọ fún ọkunrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ.” Ó bá nà án. Ọwọ́ rẹ̀ bá bọ́ sípò gẹ́gẹ́ bí ekeji. Àwọn Farisi bá jáde lọ láti gbèrò nípa rẹ̀, bí wọn óo ṣe lè pa á. Nígbà tí Jesu mọ̀ bẹ́ẹ̀, ó bá kúrò níbẹ̀. Ọpọlọpọ eniyan sì tẹ̀lé e, ó sì wo gbogbo wọn sàn. Ó kìlọ̀ fún wọn kí wọn má ṣe polongo òun, kí ọ̀rọ̀ tí wolii Aisaya sọ lè ṣẹ pé, “Wo ọmọ mi tí mo yàn, àyànfẹ́ mi, ẹni tí ọkàn mi yọ̀ mọ́ Èmi óo fi Ẹ̀mí mi sí i lára, yóo kéde ìdájọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Juu. Kò ní ṣàròyé, bẹ́ẹ̀ ni kò ní pariwo, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kò ní gbọ́ ohùn rẹ̀ ní títì. Kò ní dá igi tẹ́ẹ́rẹ́ tí ó tẹ̀ sí meji. Kò ní pa iná tí ó ń jó bẹ́lúbẹ́lú, títí ìdájọ́ òdodo rẹ̀ yóo fi borí. Ninu orúkọ rẹ̀ ni àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Juu yóo ní ìrètí.” Nígbà náà wọ́n mú ẹnìkan wá sọ́dọ̀ Jesu tí ó ní ẹ̀mí èṣù; ẹ̀mí èṣù yìí ti fọ́ ọ lójú, ó sì mú kí ó yadi. Jesu bá wò ó sàn; ọkunrin náà bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, ó sì ríran. Ẹnu ya gbogbo àwọn eniyan, wọ́n ń wí pé, “Ó ha lè jẹ́ pé ọmọ Dafidi nìyí bí?” Ṣugbọn nígbà tí àwọn Farisi gbọ́, wọ́n ní, “Ojú lásán kọ́ ni ọkunrin yìí fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde; agbára Beelisebulu, olórí àwọn ẹ̀mí èṣù ni ó ń lò.” Ṣugbọn Jesu mọ ohun tí wọn ń rò. Ó bá sọ fún wọn pé, “Gbogbo ìjọba tí ó bá gbé ogun ti ara rẹ̀ yóo parun. Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo ìlúkílùú tabi ilékílé tí àwọn eniyan ibẹ̀ bá ń bá ara wọn jà yóo tú. Bí Satani bá ń lé Satani jáde, ara rẹ̀ ni ó ń gbé ogun tì. Báwo ni ìjọba rẹ̀ ṣe lè dúró? Bí ó bá jẹ́ pé agbára Beelisebulu ni èmi fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, agbára wo ni àwọn ọmọ yín fi ń lé wọn jáde? Nítorí náà, àwọn ọmọ yín ni yóo ṣe onídàájọ́ yín. Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé nípa Ẹ̀mí Ọlọrun ni mo fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, a jẹ́ pé ìjọba Ọlọrun ti dé ba yín. “Báwo ni ẹnìkan ṣe lè wọ ilé alágbára lọ, kí ó kó o lẹ́rù, bí kò bá kọ́kọ́ de alágbára náà? Bí ó bá kọ́kọ́ dè é ni yóo tó lè kó o lẹ́rù. “Ẹni tí kò bá ṣe tèmi, ó lòdì sí mi. Ẹni tí kò bá máa bá mi kó nǹkan jọ, ó ń fọ́nká ni. Ìdí nìyí tí mo fi sọ fun yín pé gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ati gbogbo ìsọ̀rọ̀ òdì ni a óo dárí rẹ̀ ji eniyan; ṣugbọn ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí Ẹ̀mí Mímọ́ kò ní rí ìdáríjì. Ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ tí kò dára sí Ọmọ-Eniyan yóo rí ìdáríjì. Ṣugbọn ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ tí kò dára sí Ẹ̀mí Mímọ́ kò ní rí ìdáríjì láyé yìí ati ní ayé tí ń bọ. “Bákan-meji ni. Ninu kí ẹ tọ́jú igi, kí ó dára, kí èso rẹ̀ sì dára, tabi kí ẹ ba igi jẹ́, kí èso rẹ̀ náà sì bàjẹ́. Èso igi ni a fi ń mọ igi. Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀ yìí! Báwo ni ọ̀rọ̀ yín ti ṣe lè dára nígbà tí ẹ̀yin fúnra yín kò dára? Nítorí ohun tí ó bá kún inú ọkàn ni ẹnu ń sọ jáde. Ẹni rere a máa sọ ọ̀rọ̀ rere jáde láti inú ìṣúra rere; eniyan burúkú a sì máa sọ ọ̀rọ̀ burúkú jáde láti inú ìṣúra burúkú. “Ṣugbọn mo sọ fun yín pé gbogbo ọ̀rọ̀ tí eniyan bá ń sọ láì ronú ni yóo dáhùn fún ní ọjọ́ ìdájọ́. Nítorí nípa ọ̀rọ̀ rẹ ni a óo fi dá ọ láre; nípa ọ̀rọ̀ rẹ ni a óo sì fi dá ọ lẹ́bi.” Ní àkókò náà ni àwọn kan ninu àwọn amòfin ati ninu àwọn Farisi bi í pé, “Olùkọ́ni, a fẹ́ rí àmì láti ọwọ́ rẹ.” Ṣugbọn Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ìran burúkú ati ìran oníbọkúbọ ń wá àmì. Kò sí àmì kan tí a óo fi fún un àfi àmì Jona wolii. Nítorí bí Jona ti wà ninu ẹja ńlá fún ọjọ́ mẹta tọ̀sán-tòru, bẹ́ẹ̀ ni Ọmọ-Eniyan yóo wà ninu ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹta, tọ̀sán-tòru. Àwọn ará Ninefe yóo ko ìran yìí lójú ní ìdájọ́, wọn yóo sì dá a lẹ́bi. Nítorí wọ́n ronupiwada nítorí iwaasu tí Jona wà fún wọn. Wò ó, ẹni tí ó ju Jona lọ ló wà níhìn-ín. Ọbabinrin láti ilẹ̀ gúsù yóo ko ìran yìí lójú ní ìdájọ́ yóo sì dá a lẹ́bi. Nítorí ó wá láti ọ̀nà jíjìn láti gbọ́ ọgbọ́n Solomoni. Ẹ wò ó, ẹni tí ó ju Solomoni lọ ló wà níhìn-ín. “Nígbà tí ẹ̀mí èṣù jáde kúrò ninu ẹnìkan, ó bẹ̀rẹ̀ sí wá ilẹ̀ gbígbẹ láti sinmi. Ó ń wá ibi tí yóo fi ṣe ibùgbé, ṣugbọn kò rí. Ó bá ni, ‘N óo tún pada sí ilé mi, níbi tí mo ti jáde kúrò.’ Nígbà tí ó débẹ̀, ó rí i pé ibẹ̀ ṣófo, ati pé a ti gbá a, a sì ti tọ́jú rẹ̀ dáradára. Ó bá lọ, ó kó àwọn ẹ̀mí meje mìíràn lẹ́yìn tí wọ́n burú ju òun alára lọ, wọ́n bá wọlé, wọ́n ń gbé ibẹ̀. Ìgbẹ̀yìn ẹni náà wá burú ju ti àkọ́kọ́ lọ. Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún ìran burúkú yìí.” Bí Jesu ti ń bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀ ni ìyá rẹ̀ ati àwọn arakunrin rẹ̀ bá dé, wọ́n dúró lóde, wọ́n fẹ́ bá a sọ̀rọ̀. [ Ẹnìkan sọ fún un pé, “Ìyá rẹ ati àwọn arakunrin rẹ dúró lóde, wọ́n fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀.”] Jesu dá a lóhùn pé, “Ta ni ìyá mi? Àwọn ta sì ni arakunrin mi?” Ó bá nawọ́ sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní, “Wò ó ìyá mi ati àwọn arakunrin mi nìwọ̀nyí. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run, òun ni arakunrin mi ati arabinrin mi ati ìyá mi.” Ní ọjọ́ kan náà, Jesu jáde kúrò nílé, ó lọ jókòó létí òkun. Ọ̀pọ̀ eniyan péjọ sọ́dọ̀ rẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi wọ inú ọkọ̀ ojú omi kan. Ó jókòó níbẹ̀, àwọn eniyan bá dúró ní etí òkun. Ó sọ ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ fún wọn pẹlu òwe. Ó ní: “Ní ọjọ́ kan, afunrugbin kan jáde lọ láti fúnrúgbìn. Bí ó ti ń fúnrúgbìn, àwọn irúgbìn kan bọ́ sẹ́bàá ọ̀nà. Àwọn ẹyẹ bá wá ṣà á jẹ. Àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sórí ilẹ̀ olókùúta tí kò ní erùpẹ̀ pupọ. Lọ́gán ó yọ sókè, nítorí kò ní erùpẹ̀ tí ó jinlẹ̀. Ṣugbọn nígbà tí oòrùn mú, ó jó o pa, nítorí kò ní gbòǹgbò tí ó jinlẹ̀; ó bá rọ. Àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sáàrin igi ẹlẹ́gùn-ún. Nígbà tí wọ́n yọ, ẹ̀gún fún wọn pa. Ṣugbọn àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sórí ilẹ̀ rere, wọ́n sì ń so èso, àwọn mìíràn ń so ọgọọgọrun-un, àwọn mìíràn ọgọọgọta, àwọn mìíràn, ọgbọọgbọn. “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́!” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, “Kí ló dé tí o fi ń fi òwe bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀?” Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a fi àṣírí ìmọ̀ ìjọba ọ̀run hàn, a kò fihan àwọn yòókù wọnyi. Nítorí ẹni tí ó bá ní nǹkan, òun ni a óo tún fún sí i, kí ó lè ní ànító ati àníṣẹ́kù. Ẹni tí kò bá sì ní, a óo gba ìwọ̀nba díẹ̀ tí ó ní lọ́wọ́ rẹ̀. Ìdí tí mo fi ń fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ nìyí, nítorí wọ́n lajú sílẹ̀ ni, ṣugbọn wọn kò ríran. Wọ́n ní etí, ṣugbọn wọn kò gbọ́ràn, bẹ́ẹ̀ ni òye kò yé wọn. Báyìí ni àsọtẹ́lẹ̀ Aisaya ṣe ṣẹ sí wọn lára, nígbà tí ó sọ pé. ‘Ní ti gbígbọ́, ẹ óo gbọ́, ṣugbọn kò ní ye yín; ní ti pé kí ẹ ríran, ẹ óo wò títí, ṣugbọn ẹ kò ní rí nǹkankan. Ọkàn àwọn eniyan yìí ti le, etí wọn ti di, wọ́n sì ti di ojú wọn. Kí wọn má baà fi ojú wọn ríran, kí wọn má baà fi etí wọn gbọ́ràn, kí wọn má baà mòye, kí wọn má baà yipada, kí n wá gbà wọ́n là.’ “Ṣugbọn ẹ̀yin ṣe oríire tí ojú yín ríran, tí etí yín sì gbọ́ràn. Nítorí mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ọ̀pọ̀ àwọn wolii ati àwọn olódodo dàníyàn láti rí àwọn nǹkan tí ẹ̀ ń rí, ṣugbọn wọn kò rí wọn; wọ́n fẹ́ gbọ́ àwọn ohun tí ẹ̀ ń gbọ́ ṣugbọn wọn kò gbọ́. “Ẹ gbọ́ ìtumọ̀ òwe afunrugbin. Ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ìjọba ọ̀run, tí nǹkan tí ó gbọ́ kò yé e, tí èṣù wá, tí ó mú ohun tí a gbìn sọ́kàn rẹ̀ lọ: òun ni irúgbìn ti ẹ̀bá ọ̀nà. Irúgbìn ti orí ilẹ̀ olókùúta ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ó fi tayọ̀tayọ̀ gbà á lẹsẹkẹsẹ. Ṣugbọn nítorí kò ní gbòǹgbò ninu ara rẹ̀, ọ̀rọ̀ náà yóo wà fún ìgbà díẹ̀. Nígbà tí inúnibíni tabi ìṣòro bá dé nítorí ọ̀rọ̀ náà, lẹsẹkẹsẹ a kùnà. Ti ààrin igi ẹlẹ́gùn-ún ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí àníyàn ayé yìí ati ìtànjẹ ọrọ̀ fún ọ̀rọ̀ náà pa, tí kò fi so èso. Ṣugbọn èyí tí a fún sórí ilẹ̀ rere ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ọ̀rọ̀ náà yé, tí ó wá ń so èso, nígbà mìíràn, ọgọrun-un; nígbà mìíràn, ọgọta; nígbà mìíràn, ọgbọ̀n.” Ó tún pa òwe mìíràn fún wọn. Ó ní, “Bí ìjọba ọ̀run ti rí nìyí. Ó dàbí ọkunrin kan tí ó gbin irúgbìn rere sí oko rẹ̀. Nígbà tí àwọn eniyan sùn, ọ̀tá rẹ̀ wá, ó gbin èpò sáàrin ọkà, ó bá lọ. Nígbà tí ọkà dàgbà, tí ó yọ ọmọ, èpò náà dàgbà. Àwọn ẹrú baálé náà bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, ‘Alàgbà, ṣebí irúgbìn rere ni o gbìn sí oko, èpò ti ṣe débẹ̀?’ Ó dá wọn lóhùn pé, ‘Ọ̀tá ni ó ṣe èyí.’ Àwọn ẹrú rẹ̀ ní, ‘Ṣé kí á lọ tu wọ́n dànù?’ Ó bá dá wọn lóhùn pé, ‘Rárá o! Bí ẹ bá wí pé ẹ̀ ń tu èpò, ẹ óo tu ọkà náà. Ẹ jẹ́ kí àwọn mejeeji jọ dàgbà pọ̀ títí di ìgbà ìkórè. Ní àkókò ìkórè, n óo sọ fún àwọn olùkórè pé: ẹ kọ́ kó èpò jọ, kí ẹ dì wọ́n nítìí-nítìí, kí ẹ dáná sun ún. Kí ẹ wá kó ọkà jọ sinu abà mi.’ ” Ó tún pa òwe mìíràn fún wọn. Ó ní, “Báyìí ni ìjọba ọ̀run rí. Ó dàbí wóró musitadi tí ẹnìkan gbìn sinu oko rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni ó kéré jùlọ ninu gbogbo irúgbìn, sibẹ nígbà tí ó bá dàgbà, a tóbi ju gbogbo ewébẹ̀ lọ. A di igi, tí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run óo wá ṣe ìtẹ́ wọn lára ẹ̀ka rẹ̀.” Ó tún pa òwe mìíràn fún wọn. Ó ní, “Ìjọba ọ̀run dàbí ìwúkàrà tí obinrin kan mú, tí ó pò mọ́ òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun ńláńlá mẹta títí gbogbo rẹ̀ fi wú sókè.” Jesu sọ gbogbo nǹkan wọnyi fún àwọn eniyan ní òwe. Kò sọ ohunkohun fún wọn láì lo òwe; kí ọ̀rọ̀ tí wolii ti sọ lè ṣẹ, nígbà tí ó sọ pé, “Bí òwe bí òwe ni ọ̀rọ̀ mi yóo jẹ́. N óo sọ àwọn ohun tí ó ti wà ní àṣírí láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé.” Nígbà tí Jesu kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan, ó lọ sinu ilé. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sọ pé, “Ṣe àlàyé òwe èpò inú oko fún wa.” Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹni tí ó fúnrúgbìn rere ni Ọmọ-Eniyan. Ayé ni oko tí ó fúnrúgbìn sí. Irúgbìn rere ni àwọn ọmọ ìjọba ọ̀run. Èpò ni àwọn ọmọ èṣù. Ọ̀tá tí ó fọ́n èpò ni èṣù. Ìkórè ni ìgbẹ̀yìn ayé. Àwọn angẹli ni olùkórè. Nítorí náà, bí wọn tíí kó èpò jọ tí wọn ń sun ún ninu iná, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí ní ìgbẹ̀yìn ayé. Ọmọ-Eniyan yóo rán àwọn angẹli rẹ̀, wọn yóo kó gbogbo àwọn amúni-ṣìnà ati àwọn arúfin kúrò ninu ìjọba rẹ̀. Wọn yóo sọ wọ́n sinu iná ìléru. Níbẹ̀ ni ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà. Àwọn olódodo yóo wá máa ràn bí oòrùn ninu ìjọba Baba wọn. Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́. “Báyìí ni ìjọba ọ̀run rí. Ó dàbí ìṣúra iyebíye kan tí wọ́n fi pamọ́ ninu ilẹ̀. Nígbà tí ẹnìkan rí i, ó bò ó mọ́lẹ̀, ó lọ tayọ̀tayọ̀, ó ta ohun gbogbo tí ó ní, ó bá ra ilẹ̀ náà. “Báyìí tún ni ìjọba ọ̀run rí. Ó dàbí ọkunrin oníṣòwò kan tí ó ń wá ìlẹ̀kẹ̀ olówó iyebíye kan. Nígbà tí ó rí ọ̀kan tí ó dára pupọ, ó lọ ta ohun gbogbo tí ó ní, ó bá rà á. “Báyìí tún ni ìjọba ọ̀run rí. Ó dàbí àwọ̀n tí a dà sinu òkun, tí ó kó oríṣìíríṣìí ẹja. Nígbà tí ó kún, wọ́n fà á lọ sí èbúté, wọ́n jókòó, wọ́n ṣa àwọn ẹja tí ó dára jọ sinu garawa, wọ́n sì da àwọn tí kò wúlò nù. Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí ní ìgbẹ̀yìn ayé. Àwọn angẹli yóo wá, wọn óo yanjú àwọn eniyan burúkú kúrò láàrin àwọn olódodo, wọn yóo jù wọ́n sinu iná ìléru. Níbẹ̀ ni ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà.” Jesu bi wọ́n pé, “Ṣé gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi ye yín?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.” Ó wá sọ fún wọn pé, “Nítorí èyí ni amòfin tí ó bá ti kọ́ nípa ìjọba ọ̀run ṣe dàbí baálé ilé kan, tí ó ń mú nǹkan titun ati nǹkan àtijọ́ jáde láti inú àpò ìṣúra rẹ̀.” Lẹ́yìn tí Jesu ti parí gbogbo àwọn òwe wọnyi, ó kúrò níbẹ̀. Nígbà tí ó dé ìlú baba rẹ̀, ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu ilé ìpàdé wọn lọ́nà tí ó yà wọ́n lẹ́nu. Wọ́n ń sọ pé, “Níbo ni eléyìí ti ní irú ọgbọ́n yìí? Níbo ni ó ti rí agbára láti ṣiṣẹ́ ìyanu báyìí? Àbí ọmọ gbẹ́nà-gbẹ́nà yẹn kọ́ ni? Tí orúkọ ìyá rẹ̀ ń jẹ́ Maria, tí àwọn arakunrin rẹ̀ ń jẹ́ Jakọbu ati Josẹfu ati Simoni ati Judasi? Gbogbo àwọn arabinrin rẹ̀ kọ́ ni wọ́n wà lọ́dọ̀ wa níhìn-ín? Níbo ni ó wá ti rí gbogbo nǹkan wọnyi?” Wọ́n sì kọ̀ ọ́. Ṣugbọn Jesu sọ fún wọn pé, “Kò sí wolii tí kò níyì àfi ní ìlú baba rẹ̀ ati ní ilé rẹ̀.” Kò lè ṣe iṣẹ́ ìyanu pupọ níbẹ̀ nítorí wọn kò ní igbagbọ. Ní àkókò náà, Hẹrọdu ọba gbúròó Jesu. Ó wí fún àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ pé, “Johanu Onítẹ̀bọmi ni èyí. Òun ni ó jí dìde kúrò ninu òkú. Ìdí rẹ̀ nìyí tí ó fi ní agbára láti lè ṣe iṣẹ́ ìyanu.” Nítorí Hẹrọdu yìí ni ó ti pàṣẹ pé kí wọ́n mú Johanu, kí wọ́n dè é, kí wọ́n sì fi í sẹ́wọ̀n nítorí ọ̀rọ̀ Hẹrọdiasi, iyawo Filipi, arakunrin Hẹrọdu. Nítorí Johanu sọ fún Hẹrọdu pé kò tọ́ fún un láti fi Hẹrọdiasi ṣaya. Hẹrọdu fẹ́ pa á, ṣugbọn ó bẹ̀rù àwọn eniyan, nítorí wọ́n gbà pé wolii ni Johanu. Nígbà tí Hẹrọdu ń ṣe ọjọ́ ìbí rẹ̀, ọdọmọbinrin Hẹrọdiasi bẹ̀rẹ̀ sí jó lójú agbo. Èyí dùn mọ́ Hẹrọdu ninu tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi fi ìbúra ṣe ìlérí láti fún un ní ohunkohun tí ó bá bèèrè. Lẹ́yìn tí ìyá ọmọbinrin yìí ti kọ́ ọ ní ohun tí yóo bèèrè, ó ní, “Gbé orí Johanu Onítẹ̀bọmi wá fún mi nisinsinyii ninu àwo pẹrẹsẹ kan.” Ó dun ọba, ṣugbọn nítorí pé ó ti búra, ati nítorí àwọn tí ó wà níbi àsè, ó gbà láti fi fún un. Ọba bá ranṣẹ pé kí wọ́n bẹ́ Johanu lórí ninu ẹ̀wọ̀n tí ó wá. Wọ́n gbé orí rẹ̀ wá ninu àwo pẹrẹsẹ, wọ́n gbé e fún ọdọmọbinrin náà. Ó bá lọ gbé e fún ìyá rẹ̀. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu bá wá, wọ́n gbé òkú rẹ̀ lọ, wọ́n sin ín; wọ́n sì lọ ròyìn fún Jesu. Nígbà tí Jesu gbọ́, ó wọ ọkọ̀ ojú omi kúrò níbẹ̀ lọ sí ibìkan tí eniyan kò sí, kí ó lè dá wà. Nígbà tí àwọn eniyan gbọ́, wọ́n gba ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ láti ìlú wọn, wọ́n tẹ̀lé e. Bí ó ti ń gúnlẹ̀, ó rí ọ̀pọ̀ eniyan. Àánú wọn ṣe é, ó bá wo àwọn tí wọ́n ṣàìsàn ninu wọn sàn. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n ní, “Aṣálẹ̀ ni ibí yìí, ọjọ́ sì ti lọ. Fi àwọn eniyan wọnyi sílẹ̀ kí wọ́n lè lọ ra oúnjẹ fún ara wọn ninu àwọn ìletò.” Ṣugbọn Jesu sọ fún wọn pé, “Kò yẹ kí wọ́n lọ; ẹ fún wọn ní oúnjẹ jẹ.” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Kò sí oúnjẹ níhìn-ín, àfi burẹdi marun-un ati ẹja meji.” Ó ní, “Ẹ kó wọn wá fún mi níhìn-ín.” Ó bá pàṣẹ pé kí àwọn eniyan jókòó lórí koríko. Ó mú burẹdi marun-un náà ati ẹja meji; ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó dúpẹ́, ó bá bù wọ́n, ó kó wọn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá pín in fún àwọn eniyan. Gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó, àjẹkù sì kún apẹ̀rẹ̀ mejila. Àwọn eniyan tí ó jẹun tó ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) ọkunrin láì ka àwọn obinrin ati àwọn ọmọde. Lẹsẹkẹsẹ, ó bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọn wọ ọkọ̀ ojú omi ṣáájú òun lọ sí òdìkejì, nígbà tí ó ń tú àwọn eniyan ká. Nígbà tí ó tú wọn ká tán, ó gun orí òkè lọ gbadura, òun nìkan. Nígbà tí alẹ́ lẹ́, òun nìkan ni ó wà níbẹ̀. Ọkọ̀ ti kúrò ní èbúté, ó ti bọ́ sí agbami. Ìgbì omi wá ń dààmú ọkọ̀, nítorí afẹ́fẹ́ ṣọwọ́ òdì sí wọn. Nígbà tí ó di nǹkan bí agogo mẹta òru, Jesu ń bọ̀ lọ́dọ̀ wọn, ó ń rìn lójú omi òkun. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i tí ó ń rìn lójú omi, ẹ̀rù bà wọ́n gan-an, wọ́n ń sọ pé, “Iwin ni!” Wọ́n bá kígbe, nítorí ẹ̀rù bà wọ́n. Lẹsẹkẹsẹ Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ ṣe ara gírí. Èmi ni. Ẹ má bẹ̀rù!” Peteru sọ fún un pé, “Oluwa, bí ó bá jẹ́ pé ìwọ ni, sọ pé kí n máa rìn bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ lójú omi.” Jesu bá sọ fún un pé, “Máa bọ̀!” Ni Peteru bá sọ̀kalẹ̀ ninu ọkọ̀, ó rìn lójú omi lọ sọ́dọ̀ Jesu. Ṣugbọn nígbà tí ó rí i tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́, ẹ̀rù bà á, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí rì. Ó bá kígbe pé, “Oluwa, gbà mí!” Lẹsẹkẹsẹ Jesu bá fà á lọ́wọ́, ó sọ fún un pé, “Ìwọ onigbagbọ kékeré yìí! Kí ni ó mú ọ ṣe iyè meji?” Bí wọ́n ti wọ inú ọkọ́ ni afẹ́fẹ́ bá rọlẹ̀. Àwọn tí ó wà ninu ọkọ̀ júbà rẹ̀, wọ́n ń sọ pé, “Lóòótọ́, Ọmọ Ọlọrun ni ọ́!” Lẹ́yìn tí wọ́n ti gúnlẹ̀, wọ́n dé ilẹ̀ Genesarẹti. Àwọn eniyan ibẹ̀ ti dá a mọ̀, wọ́n bá ranṣẹ lọ sí gbogbo agbègbè ibẹ̀; wọ́n gbé gbogbo àwọn tí ara wọn kò dá wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Wọ́n ń bẹ̀ ẹ́ pé kí wọn sá lè fi ọwọ́ kan etí ẹ̀wù rẹ̀. Gbogbo àwọn tí wọ́n fi ọwọ́ kàn án ni ó mú lára dá. Nígbà náà ni àwọn Farisi ati àwọn amòfin wá sọ́dọ̀ Jesu láti Jerusalẹmu, wọ́n bi í pé, “Kí ló dé tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kò fi tẹ̀lé àṣà tí àwọn baba wa fi lé wa lọ́wọ́? Nítorí wọn kì í wẹ ọwọ́ wọn nígbà tí wọ́n bá fẹ́ jẹun.” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ̀yin náà ṣe ń fi àṣà ìbílẹ̀ yín rú òfin Ọlọrun? Nítorí Ọlọrun sọ pé, ‘Bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ’; ati pé, ‘Ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ burúkú sí baba tabi ìyá rẹ̀, pípa ni kí wọ́n pa á.’ Ṣugbọn ẹ̀yin sọ pé, bí ẹnikẹ́ni bá sọ fún baba tabi ìyá rẹ̀ pé, ‘Mo ti fi ohun tí ò bá fi jẹ anfaani lára mi tọrẹ fún Ọlọrun,’ kò tún níláti bọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀ mọ́. Báyìí ni ẹ fi àṣà ìbílẹ̀ yín yí ọ̀rọ̀ Ọlọrun po. Ẹ̀yin alaiṣootọ! Òtítọ́ ni Aisaya ti sọtẹ́lẹ̀ nípa yín nígbà tí ó wí pé, ‘Ọlọrun sọ pé: Ẹnu lásán ni àwọn eniyan wọnyi fi ń bọlá fún mi, ọkàn wọn jìnnà pupọ sí mi. Asán ni sísìn tí wọn ń sìn mí, ìlànà eniyan ni wọ́n fi ń kọ́ni bí ẹni pé òfin Ọlọrun ni.’ ” Ó wá pe àwọn eniyan jọ, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gbọ́, kí ó sì ye yín. Kì í ṣe ohun tí ó ń wọ ẹnu ẹni lọ ni ó ń sọni di aláìmọ́, bíkòṣe ohun tí ó ń jáde láti ẹnu wá ni ó ń sọ eniyan di aláìmọ́.” Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sọ fún un pé, “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé nígbà tí àwọn Farisi gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, ó bí wọn ninu?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Gbogbo igi tí Baba mi tí ń bẹ lọ́run kò bá gbìn ni a óo hú dànù. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀. Afọ́jú tí ó ń fọ̀nà hanni ni wọ́n. Bí afọ́jú bá ń fọ̀nà han afọ́jú, àwọn mejeeji yóo jìn sinu kòtò.” Peteru sọ fún un pé, “Túmọ̀ òwe yìí fún wa.” Jesu dá a lóhùn pé, “Kò ì tíì yé ẹ̀yin náà títí di ìwòyí? Kò ye yín pé ikùn ni gbogbo ohun tí eniyan bá fi sí ẹnu ń lọ ati pé eniyan óo tún yà á jáde? Ṣugbọn ohun tí eniyan bá sọ láti inú ọkàn rẹ̀ wá, èyí ni ó ń sọ eniyan di aláìmọ́. Nítorí láti inú ọkàn ni èrò burúkú ti ń jáde wá: ìpànìyàn, àgbèrè, ìṣekúṣe, olè jíjà, ìjẹ́rìí èké, ìsọkúsọ. Àwọn nǹkan wọnyi ni wọ́n ń sọ eniyan di aláìmọ́; kí eniyan jẹun láì wẹ ọwọ́ kò lè sọ eniyan di aláìmọ́.” Jesu jáde kúrò níbẹ̀, ó lọ sí agbègbè Tire ati Sidoni. Obinrin Kenaani kan tí ó ń gbé ibẹ̀ bá jáde, ó ń kígbe pé, “Ṣàánú mi, Oluwa, ọmọ Dafidi. Ẹ̀mí èṣù ní ń da ọdọmọbinrin mi láàmú.” Ṣugbọn Jesu kò dá a lóhùn. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá wá sọ fún un pé, “Lé obinrin yìí lọ, nítorí ó ń pariwo tẹ̀lé wa lẹ́yìn.” Jesu bá dáhùn pé, “Kìkì àwọn aguntan tí ó sọnù, àní ìdílé Israẹli nìkan ni a rán mi sí.” Ṣugbọn obinrin náà wá, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Oluwa, ràn mí lọ́wọ́.” Ṣugbọn Jesu dá a lóhùn pé, “Kò dára láti sọ oúnjẹ ọmọ eniyan sóde sí àwọn ajá!” Obinrin náà ní, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa. Ṣugbọn àwọn ajá a máa jẹ ẹ̀ẹ́rún oúnjẹ tí ó bọ́ sílẹ̀ láti inú àwo oúnjẹ oluwa wọn.” Nígbà náà ni Jesu sọ fún un pé, “Obinrin yìí! Igbagbọ rẹ tóbi gidi. Kí ó rí fún ọ bí o ti fẹ́.” Ara ọdọmọbinrin rẹ̀ bá dá láti àkókò náà. Nígbà tí Jesu kúrò níbẹ̀, ó lọ sí ẹ̀bá òkun Galili; ó gun orí òkè lọ, ó bá jókòó níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ eniyan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n gbé àwọn arọ wá, ati àwọn afọ́jú, àwọn amúkùn-ún ati àwọn odi, ati ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn mìíràn. Wọ́n gbé wọn kalẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bá wò wọ́n sàn. Ẹnu ya àwọn eniyan, nígbà tí wọ́n rí i tí àwọn odi ń sọ̀rọ̀, tí àwọn amúkùn-ún di alára líle, tí àwọn arọ ń rìn, tí àwọn afọ́jú sì ń ríran. Wọ́n fi ìyìn fún Ọlọrun Israẹli. Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ́dọ̀ ó ní, “Àánú àwọn eniyan wọnyi ń ṣe mí, nítorí ó di ọjọ́ mẹta tí wọ́n ti wà lọ́dọ̀ mi; wọn kò ní oúnjẹ mọ́. N kò fẹ́ tú wọn ká pẹlu ebi ninu, kí òòyì má baà gbé wọn lọ́nà.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Níbo ni a óo ti rí oúnjẹ ní aṣálẹ̀ yìí tí yóo yó àwọn eniyan tí ó pọ̀ tó báyìí?” Jesu bi wọ́n pé, “Burẹdi mélòó ni ẹ ní?” Wọ́n ní, “Meje, ati ẹja kéékèèké díẹ̀.” Jesu pàṣẹ kí àwọn eniyan jókòó nílẹ̀. Ó wá mú burẹdi meje náà ati àwọn ẹja náà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó bù wọ́n, ó bá kó wọn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá pín wọn fún àwọn eniyan. Gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó; wọ́n sì kó àjẹkù wọn jọ, ó kún apẹ̀rẹ̀ meje. Àwọn tí wọ́n jẹ oúnjẹ jẹ́ ẹgbaaji (4,000) ọkunrin láì ka àwọn obinrin ati àwọn ọmọde. Lẹ́yìn tí Jesu ti tú àwọn eniyan ká, ó wọ inú ọkọ̀ ojú omi, ó bá lọ sí agbègbè Magadani. Àwọn Farisi ati àwọn Sadusi wá sọ́dọ̀ Jesu, wọ́n ń dán an wò, wọ́n ní kí ó fi àmì láti ọ̀run han àwọn. Ó dá wọn lóhùn pé, “Nígbà tí ọjọ́ bá rọ̀, ẹ máa ń sọ pé, ‘Ojú ọjọ́ dára, nítorí ojú ọ̀run pupa.’ Ní òwúrọ̀ ẹ̀wẹ̀, ẹ máa ń sọ pé, ‘Ìjì yóo jà lónìí nítorí pé ojú ọ̀run pupa, ó sì ṣú.’ Ẹ mọ ohun tí àmì ojú ọ̀run jẹ́, ṣugbọn ẹ kò mọ àwọn àmì àkókò yìí. Ìran burúkú ati oníbọkúbọ ń wá àmì; ṣugbọn a kò ní fi àmì kan fún un, àfi àmì Jona.” Ó bá fi wọ́n sílẹ̀ ó sì bá tirẹ̀ lọ. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rékọjá sí òdìkejì òkun, wọ́n gbàgbé láti mú oúnjẹ lọ́wọ́. Jesu wá sọ fún wọn pé, “Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ sì ṣe gáfárà fún ìwúkàrà àwọn Farisi ati àwọn Sadusi.” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí wí láàrin ara wọn pé, “Nítorí a kò mú oúnjẹ lọ́wọ́ wá ni ó ṣe sọ bẹ́ẹ̀.” Ṣugbọn Jesu mọ ohun tí wọn ń sọ, ó ní, “Kí ló dé tí ẹ fi ń sọ láàrin ara yín nípa oúnjẹ tí ẹ kò ní, ẹ̀yin onigbagbọ kékeré? Òye kò ì tíì ye yín sibẹ? Ẹ kò ranti burẹdi marun-un tí mo fi bọ́ ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) eniyan ati iye agbọ̀n àjẹkù tí ẹ kó jọ? Ti burẹdi meje ńkọ́, tí mo fi bọ́ ẹgbaaji (4,000) eniyan ati iye apẹ̀rẹ̀ àjẹkù tí ẹ kó jọ? Kí ló dé tí kò fi ye yín pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ oúnjẹ ni mò ń sọ? Ẹ ṣe gáfárà fún ìwúkàrà àwọn Farisi ati Sadusi.” Nígbà náà ni ó wá yé wọn pé kì í ṣe ti ìwúkàrà tí à ń fi sinu burẹdi ni ó ń sọ, ti ẹ̀kọ́ àwọn Farisi ati Sadusi ni ó ń sọ. Nígbà tí Jesu dé agbègbè ìlú Kesaria ti Filipi, ó bi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ta ni àwọn eniyan rò pé Ọmọ-Eniyan jẹ́?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwọn kan ní Johanu Onítẹ̀bọmi ni. Àwọn mìíràn ní Elija ni. Àwọn mìíràn tún ní Jeremaya ni tabi ọ̀kan ninu àwọn wolii.” Ó wá bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ńkọ́? Ta ni ẹ rò pé mo jẹ́?” Simoni Peteru dá a lóhùn pé, “Ìwọ ni Mesaya, Ọmọ Ọlọrun Alààyè.” Jesu sọ fún un pé, “O káre, Simoni, ọmọ Jona, nítorí kì í ṣe eniyan ni ó fi èyí hàn ọ́ bíkòṣe Baba mi tí ń bẹ lọ́run. Mo sọ fún ọ pé: Peteru ni ọ́, ní orí àpáta yìí ni n óo kọ́ ìjọ mi lé; agbára ikú kò ní lè ká a. N óo fún ọ ní kọ́kọ́rọ́ ìjọba ọ̀run. Ohunkohun tí o bá dè ní ayé, ó di dídè ní ọ̀run. Ohunkohun tí o bá sì tú ní ayé, ó di títú ní ọ̀run.” Nígbà náà ni Jesu wá pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọn má sọ fún ẹnikẹ́ni pé òun ni Mesaya. Láti ìgbà náà lọ ni Jesu ti bẹ̀rẹ̀ sí máa fihan àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé dandan ni kí òun lọ sí Jerusalẹmu, kí òun jìyà pupọ lọ́wọ́ àwọn àgbà ati àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin; ati pé kí wọ́n pa òun, ṣugbọn ní ọjọ́ kẹta a óo jí òun dìde. Ni Peteru bá pè é sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí bá a wí pé, “Ọlọrun má jẹ́! Oluwa, irú èyí kò ní ṣẹlẹ̀ sí ọ.” Ṣugbọn Jesu yipada, ó sọ fún Peteru pé, “Kó ara rẹ̀ kúrò níwájú mi, Satani. Ohun ìkọsẹ̀ ni o jẹ́ fún mi, nítorí o kò ro nǹkan ti Ọlọrun, ti eniyan ni ò ń rò.” Jesu bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, ó níláti sẹ́ ara rẹ̀, kí ó gbé agbelebu rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn. Nítorí ẹni tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là yóo pàdánù rẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí ó bá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nítorí mi, yóo rí i. Nítorí anfaani wo ni ó ṣe eniyan, tí ó bá jèrè gbogbo ayé yìí, tí ó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀? Tabi kí ni eniyan lè fi dípò ẹ̀mí rẹ̀? Nítorí Ọmọ-Eniyan yóo wá ninu ògo Baba rẹ̀ pẹlu àwọn angẹli rẹ̀, yóo wá fi èrè fún ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé àwọn kan wà láàrin àwọn tí ó dúró níhìn-ín, tí kò ní kú títí wọn óo fi rí Ọmọ-Eniyan tí yóo máa bọ̀ wá gẹ́gẹ́ bí Ọba.” Lẹ́yìn ọjọ́ mẹfa, Jesu mú Peteru ati Jakọbu ati Johanu arakunrin Jakọbu, wọ́n lọ sí orí òkè gíga kan; àwọn nìkan wà níbẹ̀. Jesu bá para dà lójú wọn. Ojú rẹ̀ wá ń tàn bí oòrùn. Aṣọ rẹ̀ mọ́ gbòò bí ọjọ́. Wọ́n wá rí Mose ati Elija tí wọn ń bá Jesu sọ̀rọ̀. Peteru bá sọ fún Jesu pé, “Oluwa, kì bá dára kí á máa gbé ìhín. Bí o bá fẹ́, èmi yóo pa àgọ́ mẹta síhìn-ín, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mose ati ọ̀kan fún Elija.” Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ìkùukùu kan tí ń tàn bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ohùn kan wá láti inú ìkùukùu náà wí pé, “Àyànfẹ́ ọmọ mi nìyí, inú mi dùn sí i. Ẹ máa gbọ́ tirẹ̀.” Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́, wọ́n dojúbolẹ̀, ẹ̀rù sì bà wọ́n pupọ. Jesu wá sọ́dọ̀ wọn, ó fọwọ́ kàn wọ́n, ó ní, “Ẹ dìde. Ẹ má bẹ̀rù.” Nígbà tí wọ́n gbé ojú wọn sókè, wọn kò rí ẹnikẹ́ni mọ́, àfi Jesu nìkan. Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, Jesu pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ má sọ ohun tí ẹ rí fún ẹnikẹ́ni títí a óo fi jí Ọmọ-Eniyan dìde kúrò ninu òkú.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bi í pé, “Kí ni ìdí rẹ̀ tí àwọn amòfin fi sọ pé Elija ni ó níláti kọ́kọ́ dé?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Òtítọ́ ni pé Elija yóo wá, yóo sì mú ohun gbogbo bọ̀ sípò. Ṣugbọn mo sọ fun yín, Elija ti dé, ṣugbọn àwọn eniyan kò mọ̀ ọ́n; ohun tí ó wù wọ́n ni wọ́n ṣe sí i. Bẹ́ẹ̀ náà ni Ọmọ-Eniyan yóo sì jìyà lọ́wọ́ wọn.” Ó yé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nígbà náà pé nípa Johanu Onítẹ̀bọmi ni ó ń sọ fún wọn. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ àwọn eniyan, ọkunrin kan wá sọ́dọ̀ Jesu, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó ní, “Alàgbà, ṣàánú ọmọ mi, nítorí wárápá a máa gbé e, a sì máa joró pupọ. Nítorí ní ọpọlọpọ ìgbà, a máa ṣubú lu iná; ní ọpọlọpọ ìgbà ẹ̀wẹ̀, a máa ṣubú sinu omi. Mo mú un wá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ, ṣugbọn wọn kò lè wò ó sàn.” Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin ìran alaigbagbọ ati ìran tí ó bàjẹ́ yìí, ìgbà wo ni n óo wà lọ́dọ̀ yín dà? Ìgbà wo ni n óo sì fara dà á fun yín dà? Ẹ mú ọmọ náà wá síhìn-ín.” Jesu bá pàṣẹ fún ẹ̀mí èṣù náà kí ó jáde kúrò ninu rẹ̀, ara ọmọ náà sì dá láti ìgbà náà. Nígbà tí ó yá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wá sọ́dọ̀ Jesu níkọ̀kọ̀, wọn bi í pé, “Kí ló dé tí àwa kò fi lè lé ẹ̀mí èṣù náà jáde?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Nítorí igbagbọ yín tí ó kéré ni. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé bí ẹ bá ní igbagbọ tí kò ju wóró musitadi tí ó kéré pupọ lọ, tí ẹ bá sọ fún òkè yìí pé, ‘Kúrò níbẹ̀,’ yóo sì kúrò. Kó ní sí ohun kan tí ẹ kò ní lè ṣe. [ Irú ẹ̀mí burúkú báyìí kò lè jáde àfi nípa adura ati ààwẹ̀.”] Nígbà tí wọ́n péjọ ní Galili Jesu sọ fún wọn pé, “A óo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn eniyan lọ́wọ́, wọn yóo pa á; a óo sì jí i dìde ní ọjọ́ kẹta.” Ọ̀rọ̀ yìí bà wọ́n ninu jẹ́ pupọ. Nígbà tí wọ́n dé Kapanaumu, àwọn tí ń gba owó Tẹmpili lọ sí ọ̀dọ̀ Peteru, wọ́n bi í pé, “Ṣé olùkọ́ni yín kì í san owó Tẹmpili ni?” Ó ní, “Kí ló dé? A máa san án.” Nígbà tí ó dé ilé, Jesu ló ṣáájú rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó ní, “Kí ni o rò, Simoni? Lọ́wọ́ àwọn ta ni àwọn ọba ayé ti ń gba owó-orí tabi owó-odè? Lọ́wọ́ àwọn ọmọ onílẹ̀ ni tabi lọ́wọ́ àlejò?” Peteru dáhùn pé, “Lọ́wọ́ àlejò ni.” Jesu wá sọ fún un pé, “Èyí ni pé kò kan àwọn ọmọ onílẹ̀. Sibẹ kí á má baà jẹ́ ohun ìkọsẹ̀ fún wọn, lọ sí etí òkun, ju ìwọ̀ sí omi; ẹja kinni tí o bá fà sókè, mú un, ya ẹnu rẹ̀, o óo rí owó fadaka kan níbẹ̀. Mú un kí o fi fún wọ́n fún owó tèmi ati tìrẹ.” Ní àkókò náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, “Ta ní ṣe pataki jùlọ ní ìjọba ọ̀run?” Jesu bá pe ọmọde kan, ó mú un dúró láàrin wọn, ó ní, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, bí ẹ kò bá yipada kí ẹ dàbí àwọn ọmọde, ẹ kò ní wọ ìjọba ọ̀run. Nítorí náà ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ bí ọmọde yìí, òun ni ó jẹ́ eniyan pataki jùlọ ní ìjọba ọ̀run. Ẹni tí ó bá gba ọ̀kan ninu irú àwọn ọmọde wọnyi ní orúkọ mi, èmi ni ó gbà. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ohun ìkọsẹ̀ fún ọ̀kan ninu àwọn kéékèèké wọnyi tí ó gbà mí gbọ́, ó sàn fún un kí á so ọlọ ńlá mọ́ ọn lọ́rùn, kí á sọ ọ́ sinu ibú òkun. Ìdájọ́ ńlá ń bẹ fún ayé, nítorí àwọn ohun ìkọsẹ̀. Dandan ni kí àwọn ohun ìkọsẹ̀ dé, ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ohun ìkọsẹ̀ bá ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, ó gbé! “Bí ọwọ́ tabi ẹsẹ̀ rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù. Ó sàn fún ọ kí o wọ inú ìyè pẹlu àbùkù ọwọ́ tabi ti ẹsẹ̀, jù pé kí o ní ọwọ́ meji tabi ẹsẹ̀ meji kí á sọ ọ́ sinu iná àjóòkú lọ. Bí ojú rẹ bá mú ọ kọsẹ̀ yọ ọ́ sọnù. Ó sàn fún ọ kí o wọ inú ìyè pẹlu ojú kan jù pé kí o ní ojú meji kí á sọ ọ́ sinu iná ọ̀run àpáàdì lọ. “Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe fi ojú tẹmbẹlu ọ̀kan ninu àwọn kékeré wọnyi; nítorí mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé, àwọn angẹli wọn ní ọ̀run ń wo ojú Baba mi tí ń bẹ lọ́run nígbà gbogbo. [ Nítorí Ọmọ-Eniyan wá láti gba àwọn tí ó ti sọnù là.] “Kí ni ẹ rò? Bí ọkunrin kan bá ní ọgọrun-un aguntan, tí ọ̀kan ninu wọn bá sọnù, ǹjẹ́ ọkunrin náà kò ní fi aguntan mọkandinlọgọrun-un yòókù sílẹ̀ lórí òkè, kí ó lọ wá èyí tí ó sọnù? Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, nígbà tí ó bá rí i, inú rẹ̀ yóo dùn sí i ju àwọn mọkandinlọgọrun-un tí kò sọnù lọ. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni, kì í ṣe ìfẹ́ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run pé kí ọ̀kan ninu àwọn kékeré wọnyi kí ó ṣègbé. “Bí arakunrin rẹ bá ṣẹ̀ ọ́, tètè lọ bá a sọ̀rọ̀, ìwọ rẹ̀ meji péré. Bí ó bá gbà sí ọ lẹ́nu, o ti tún sọ ọ́ di arakunrin rẹ tòótọ́. Bí kò bá gbọ́, tún lọ bá a sọ ọ́, ìwọ ati ẹnìkan tabi ẹni meji; gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ninu àkọsílẹ̀ pé, ẹ̀rí ẹnu eniyan meji tabi mẹta ni a óo fi mọ òtítọ́ gbogbo ọ̀rọ̀. Bí kò bá gba tiwọn, sọ fún ìjọ. Bí kò bá gba ti ìjọ, kà á kún alaigbagbọ tabi agbowó-odè. “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ohunkohun tí ẹ bá dè ní ayé, ó di dídè ní ọ̀run; ohunkohun tí ẹ bá tú ní ayé, ó di títú ní ọ̀run. “Mo tún sọ fun yín pé bí ẹni meji ninu yín bá fi ohùn ṣọ̀kan ní ayé nípa ohunkohun tí wọn bá bèèrè, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún wọn láti ọ̀dọ̀ Baba mi tí ń bẹ lọ́run. Nítorí níbi tí ẹni meji tabi mẹta bá péjọ ní orúkọ mi, mo wà níbẹ̀ láàrin wọn.” Nígbà náà ni Peteru wá sọ́dọ̀ Jesu, ó bi í pé, “Oluwa, ìgbà mélòó ni arakunrin mi óo ṣẹ̀ mí tí n óo dáríjì í? Ṣé kí ó tó ìgbà meje?” Jesu dá a lóhùn pé, “N kò sọ fún ọ pé ìgbà meje; ṣugbọn kí ó tó ìgbà meje lọ́nà aadọrin! Nítorí pé ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan tí ó fẹ́ yanjú owó òwò pẹlu àwọn ẹrú rẹ̀. Nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣírò owó, wọ́n mú ẹnìkan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ọ̀kẹ́ àìmọye. Kò ní ohun tí yóo fi san gbèsè yìí, nítorí náà olówó rẹ̀ pàṣẹ pé kí á ta òun ati iyawo rẹ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀ ati gbogbo ohun tí ó ní, kí á fi san gbèsè rẹ̀. Ẹrú náà bá dọ̀bálẹ̀, ó bẹ olówó rẹ̀ pé, ‘Ṣe sùúrù fún mi, n óo san gbogbo gbèsè mi fún ọ.’ Olówó rẹ̀ wá ṣàánú rẹ̀, ó bá dá a sílẹ̀, ó sì bùn ún ní owó tí ó yá. “Nígbà tí ẹrú náà jáde, ó rí ẹrú, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan tí ó jẹ ẹ́ ní eélòó kan. Ó bá dì í mú, ó fún un lọ́rùn, ó ní; ‘San gbèsè tí o jẹ mí.’ Ẹrú, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ bá dọ̀bálẹ̀, ó ń bẹ̀ ẹ́ pé, ‘Ṣe sùúrù fún mi, n óo san án fún ọ.’ Ṣugbọn kò gbà; ẹ̀wọ̀n ni ó ní kí wọ́n lọ jù ú sí títí yóo fi san gbèsè tí ó jẹ. Nígbà tí àwọn ẹrú, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yòókù rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, inú bí wọn pupọ, wọ́n bá lọ ro ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún olówó wọn. Olówó ẹrú náà bá pè é, ó sọ fún un pé, ‘Ìwọ ẹrú burúkú yìí! Mo bùn ọ́ ní adúrú gbèsè nnì nítorí o bẹ̀ mí. Kò ha yẹ kí ìwọ náà ṣàánú ẹrú, ẹlẹgbẹ́ rẹ, bí mo ti ṣàánú rẹ?’ Inú bí olówó rẹ̀, ó bá fà á fún ọ̀gá àwọn ẹlẹ́wọ̀n pé kí wọ́n sọ ọ́ sẹ́wọ̀n títí yóo fi san gbogbo gbèsè tí ó jẹ tán. “Bẹ́ẹ̀ ni Baba mi ọ̀run yóo ṣe si yín bí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín kò bá fi tọkàntọkàn dáríjì arakunrin rẹ̀.” Nígbà tí Jesu parí àwọn ọ̀rọ̀ wọnyi, ó kúrò ní Galili, ó dé ìgbèríko Judia ní òdìkejì odò Jọdani. Ọ̀pọ̀ eniyan ni ó ń tẹ̀lé e tí ó sì wòsàn níbẹ̀. Àwọn Farisi wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń dán an wò; wọ́n bi í pé, “Ǹjẹ́ ó tọ̀nà pé kí ọkunrin kọ iyawo rẹ̀ sílẹ̀ fún ìdí kankan?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ kò mọ̀ pé ẹni tí ó dá wọn ní ìbẹ̀rẹ̀, takọ-tabo ni ó dá wọn, tí ó sì wí pé, ‘Ìdí nìyí tí ọkunrin yóo fi fi baba ati ìyá rẹ́ sílẹ̀ tí yóo fara mọ́ iyawo rẹ̀. Àwọn mejeeji yóo wá di ara kan?’ Èyí ni pé wọn kì í tún ṣe ẹni meji mọ́, bíkòṣe ọ̀kan. Nítorí náà ohun tí Ọlọrun bá ti so pọ̀, eniyan kò gbọdọ̀ yà á.” Wọ́n bá tún bi í pé, “Kí ló dé tí Mose fi pàṣẹ pé kí ọkọ fún aya ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀, kí ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Nítorí líle ọkàn yín ni Mose fi gbà fun yín láti kọ aya yín sílẹ̀. Ní ìbẹ̀rẹ̀ kò rí bẹ́ẹ̀. Mo sọ fun yín pé ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ tí kò bá jẹ́ nítorí àgbèrè, tí ó bá fẹ́ ẹlòmíràn, ó ṣe àgbèrè.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Bí ọ̀ràn láàrin ọkunrin ati obinrin bá rí bẹ́ẹ̀, kò ṣe anfaani láti gbeyawo.” Ṣugbọn ó sọ fún wọn pé, “Kì í ṣe gbogbo eniyan ni ó lè gba nǹkan yìí, àfi àwọn tí Ọlọrun bá fi fún láti gbà á. Nítorí àwọn ẹlòmíràn jẹ́ akúra kí á tó bí wọn, eniyan sọ àwọn mìíràn di akúra; àwọn ẹlòmíràn sì sọ ara wọn di akúra nítorí ti ìjọba ọ̀run. Ẹni tí ó bá lè gba èyí, kí ó gbà á.” Ní àkókò yìí ni wọ́n gbé àwọn ọmọde wá sọ́dọ̀ Jesu, kí ó lè gbé ọwọ́ lé wọn, kí ó sì súre fún wọn. Ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá àwọn tí wọn gbé wọn wá wí. Ṣugbọn Jesu sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọde wá sọ́dọ̀ mi; ẹ má dí wọn lọ́nà, nítorí ti irú wọn ni ìjọba ọ̀run.” Ó bá gbé ọwọ́ lé wọn; ó sì kúrò níbẹ̀. Nígbà kan, ẹnìkan wá sọ́dọ̀ Jesu, ó bi í pé, “Olùkọ́ni, nǹkan rere wo ni kí n ṣe kí n lè ní ìyè ainipẹkun?” Jesu sọ fún un pé, “Nítorí kí ni o ṣe ń bi mí nípa ohun rere? Ẹni rere kanṣoṣo ni ó wà. Bí o bá fẹ́ wọ inú ìyè, pa àwọn òfin mọ́.” Ó bi Jesu pé, “Òfin bí irú èwo?” Jesu sọ fún un pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ pa eniyan. Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè. Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè. Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké. Bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ. Ati pé, fẹ́ràn ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ.” Ọdọmọkunrin náà sọ fún Jesu pé, “Gbogbo òfin wọnyi ni mo ti pamọ́. Kí ni ó tún kù kí n ṣe?” Jesu sọ fún un pé, “Bí o bá fẹ́ ṣe àṣepé, lọ ta dúkìá rẹ, kí o pín owó rẹ̀ fún àwọn talaka; o óo sì ní ìṣúra ní ọ̀run. Lẹ́yìn náà, máa tẹ̀lé mi.” Nígbà tí ọdọmọkunrin náà gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó kúrò níbẹ̀ pẹlu ìbànújẹ́ nítorí ó ní ọrọ̀ pupọ. Jesu bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé yóo ṣòro fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba ọ̀run. Mo tún ń wí fun yín pé yóo rọrùn fún ràkúnmí láti wọ ojú abẹ́rẹ́ jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọrun lọ.” Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́, ẹnu yà wọ́n pupọ. Wọ́n ní, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ta ni yóo rí ìgbàlà?” Jesu wò wọ́n lójú, ó sọ fún wọn pé, “Èyí kò ṣeéṣe fún eniyan; ṣugbọn ohun gbogbo ni ó ṣeéṣe fún Ọlọrun.” Peteru bá bi í pé, “Wò ó, àwa ti fi ilé ati ọ̀nà sílẹ̀, a wá ń tẹ̀lé ọ. Kí ni yóo jẹ́ èrè wa?” Jesu sọ fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, nígbà tí ó bá di àkókò àtúndá ayé, tí Ọmọ-Eniyan bá jókòó lórí ìtẹ́ ìgúnwà rẹ̀, ẹ̀yin náà tí ẹ tẹ̀lé mi yóo jókòó lórí ìtẹ́ mejila, ẹ óo máa ṣe ìdájọ́ lórí ẹ̀yà Israẹli mejila. Gbogbo ẹni tí ó bá sì fi ilé tabi arakunrin tabi arabinrin, baba tabi ìyá, ọmọ tabi ilẹ̀ sílẹ̀, nítorí orúkọ mi, yóo gba ìlọ́po-ìlọ́po ní ọ̀nà ọgọrun-un, yóo sì tún jogún ìyè ainipẹkun. Ọpọlọpọ tí ó jẹ́ ará iwájú yóo di èrò ẹ̀yìn; àwọn èrò ẹ̀yìn yóo di ará iwájú. “Ìjọba ọ̀run dàbí baálé ilé kan tí ó jáde ní òwúrọ̀ kutukutu láti lọ wá àwọn òṣìṣẹ́ sinu ọgbà àjàrà rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó ti gbà láti fún àwọn òṣìṣẹ́ náà ní owó fadaka kan fún iṣẹ́ ojúmọ́, ó ní kí wọ́n lọ ṣiṣẹ́ ninu ọgbà àjàrà òun. Ó tún jáde lọ ní agogo mẹsan-an òwúrọ̀, ó rí àwọn mìíràn tí wọn dúró ní ọjà láìṣe nǹkankan. Ó sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin náà ẹ lọ sinu ọgbà àjàrà mi, n óo sì fun yín ní ohun tí ó bá tọ́.’ Wọ́n bá lọ. Ọkunrin náà tún jáde lọ ní agogo mejila ọ̀sán ati ní agogo mẹta ọ̀sán, ó tún ṣe bákan náà. Nígbà tí ó jáde ní agogo marun-un ìrọ̀lẹ́, ó rí àwọn mìíràn tí wọn dúró, ó bi wọ́n pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi dúró láti àárọ̀ láìṣe nǹkankan?’ Wọ́n dá a lóhùn pé, ‘Nítorí ẹnikẹ́ni kò gbà wá síṣẹ́ ni.’ Ó sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin náà ẹ lọ sinu ọgbà àjàrà mi.’ “Nígbà tí ọjọ́ rọ̀, ẹni tí ó ni ọgbà àjàrà náà sọ fún iranṣẹ rẹ̀ pé, ‘Pe àwọn òṣìṣẹ́, kí o fún wọn ní owó wọn, bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn tí ó dé gbẹ̀yìn, títí dé ọ̀dọ̀ àwọn tí ó kọ́kọ́ dé.’ Nígbà tí àwọn tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní agogo marun-un ìrọ̀lẹ́ dé, wọ́n gba owó fadaka kọ̀ọ̀kan. Nígbà tí àwọn tí wọn kọ́kọ́ dé ibi iṣẹ́ dé, wọ́n rò pé wọn yóo gbà ju owó fadaka kọ̀ọ̀kan lọ. Ṣugbọn owó fadaka kọ̀ọ̀kan ni àwọn náà gbà. Nígbà tí wọ́n gbà á tán, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí ọlọ́gbà àjàrà náà. Wọ́n ní, ‘Wakati kan péré ni àwọn yìí tí wọ́n dé kẹ́yìn ṣe; o wá san iye kan náà fún àwa ati àwọn, àwa tí a ṣe iṣẹ́ àṣelàágùn ninu oòrùn gangan!’ “Ṣugbọn ọlọ́gbà àjàrà náà dá ọ̀kan ninu wọn lóhùn pé, ‘Arakunrin, n kò rẹ́ ọ jẹ. Àdéhùn owó fadaka kan ni mo bá ọ ṣe. Gba ohun tí ó tọ́ sí ọ kí o máa bá tìrẹ lọ; nítorí ó wù mí láti fún àwọn yìí tí wọ́n dé kẹ́yìn yìí ní ohun tí mo fún ọ. Àbí n kò ní ẹ̀tọ́ láti ṣe ohun ìní mi bí mo ti fẹ́? Ṣé ò ń jowú nítorí mo ní inú rere ni?’ “Bẹ́ẹ̀ gan-an ni, àwọn èrò ẹ̀yìn yóo di ará iwájú, àwọn ará iwájú yóo di èrò ẹ̀yìn.” Bí Jesu ti ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu, ní ọ̀nà, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila sí apá kan, níkọ̀kọ̀, ó sọ fún wọn pé, “Lílọ ni à ń lọ sí Jerusalẹmu yìí o, wọn óo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin lọ́wọ́, wọn óo sì dá a lẹ́bi ikú. Wọn óo fà á lé àwọn tí kì í ṣe Juu lọ́wọ́ láti fi ṣe ẹlẹ́yà, láti nà ati láti kàn mọ́ agbelebu. Ṣugbọn ní ọjọ́ kẹta a óo jí i dìde.” Nígbà náà ni ìyá àwọn ọmọ Sebede wá sọ́dọ̀ Jesu pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀. Ó kúnlẹ̀, ó ń bèèrè nǹkankan lọ́dọ̀ rẹ̀. Jesu bi í pé, “Kí ni o fẹ́?” Ó ní, “Gbà pé kí àwọn ọmọ mi mejeeji yìí jókòó pẹlu rẹ ní ìjọba rẹ, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún ekeji ní ọwọ́ òsì.” Jesu dáhùn pé, “Ẹ kò mọ ohun tí ẹ̀ ń bèèrè. Ẹ lè mu ninu ife ìrora tí èmi yóo mu?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “A lè mu ún.” Ó sọ fún wọn pé, “Lódodo ẹ óo mu ninu ife mi, ṣugbọn láti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi ati ní ọwọ́ òsì mi kò sí ní ìkáwọ́ mi láti fi fún ẹnikẹ́ni, ipò wọnyi wà fún àwọn tí a ti pèsè rẹ̀ sílẹ̀ fún láti ọ̀dọ̀ Baba mi.” Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́wàá yòókù gbọ́, inú wọn ru sí àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò meji yìí. Ṣugbọn Jesu pè wọ́n sọ́dọ̀, ó ní, “Ẹ mọ̀ pé àwọn aláṣẹ láàrin àwọn alaigbagbọ a máa jẹ ọlá lórí wọn, àwọn eniyan ńláńlá láàrin wọn a sì máa lo agbára lórí wọn. Tiyín kò ní rí bẹ́ẹ̀. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ jẹ́ pataki ninu yín níláti jẹ́ iranṣẹ yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ jẹ́ aṣaaju yóo ṣe ẹrú fun yín. Nítorí Ọmọ-Eniyan kò wá pé kí eniyan ṣe iranṣẹ fún un; ó wá láti ṣe iranṣẹ ni, ati láti fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà fún ọpọlọpọ eniyan.” Bí Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti ń jáde kúrò ní Jẹriko, ọ̀pọ̀ eniyan tẹ̀lé e. Àwọn afọ́jú meji kan jókòó lẹ́bàá ọ̀nà. Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Jesu ń kọjá lọ, wọ́n kígbe pé, “Ọmọ Dafidi, ṣàánú wa.” Ṣugbọn àwọn eniyan bá wọn wí pé kí wọ́n panu mọ́. Ṣugbọn ńṣe ni wọ́n túbọ̀ ń kígbe pé, “Oluwa ṣàánú wa, ọmọ Dafidi.” Jesu bá dúró, ó pè wọ́n, ó ní, “Kí ni ẹ fẹ́ kí n ṣe fun yín?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Oluwa, a fẹ́ kí ojú wa là ni.” Àánú wọn ṣe Jesu, ó bá fi ọwọ́ kàn wọ́n lójú. Wọ́n ríran lẹsẹkẹsẹ, wọ́n bá ń tẹ̀lé e. Nígbà tí wọ́n súnmọ́ Jerusalẹmu, tí wọ́n dé Bẹtifage ní Òkè Olifi, Jesu rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn meji lọ ṣiwaju. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí ìletò tí ó wà ní ọ̀kánkán yín yìí. Bí ẹ bá ti wọ inú rẹ̀, ẹ óo rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí wọ́n so mọ́lẹ̀, pẹlu ọmọ rẹ̀. Ẹ tú wọn, kí ẹ mú wọn wá fún mi. Bí ẹnìkan bá bi yín ní nǹkankan, ẹ dá a lóhùn pé, ‘Oluwa nílò wọn.’ Lẹsẹkẹsẹ wọn yóo jẹ́ kí ẹ mú wọn wá.” Kí ọ̀rọ̀ tí wolii nì sọ lè ṣẹ pé, “Ẹ sọ fún ọdọmọbinrin, Sioni, pé, Wo ọba rẹ tí ó ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ; pẹlu ìrẹ̀lẹ̀, ó gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àní ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ẹranko tí à ń lò láti rẹrù.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà lọ, wọ́n ṣe bí Jesu ti pàṣẹ fún wọn. Wọ́n fa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ati ọmọ rẹ̀ wá, wọ́n tẹ́ aṣọ lé wọn lórí, Jesu bá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ gùn. Ọ̀pọ̀ ninu àwọn eniyan tẹ́ aṣọ wọn sọ́nà; àwọn mìíràn ya ẹ̀ka igi, wọ́n tẹ́ wọn sọ́nà. Àwọn èrò tí ń lọ níwájú, ati àwọn tí wọn ń bọ̀ lẹ́yìn wá ń kígbe pé, “Hosana fún Ọmọ Dafidi, olùbùkún ni ẹni tí ó wá lórúkọ Oluwa. Ògo ni fún Ọlọrun lókè ọ̀run.” Nígbà tí Jesu wọ Jerusalẹmu, gbogbo ìlú mì tìtì. Àwọn ará ìlú ń bèèrè pé, “Ta nìyí?” Àwọn èrò tí ń bọ̀ wá sì dá wọn lóhùn pé, “Jesu, wolii, láti ìlú Nasarẹti ti Galili ni.” Jesu bá wọ inú Tẹmpili lọ, ó lé gbogbo àwọn tí wọn ń tà, tí wọn ń rà kúrò níbẹ̀. Ó ti tabili àwọn tí wọn ń ṣe pàṣípààrọ̀ owó ṣubú. Ó da ìsọ̀ àwọn tí wọn ń ta ẹyẹlé rú. Ó sọ fún wọn pé, “Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Ilé adura ni ilé mi jẹ́,’ ṣugbọn ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibi tí àwọn ọlọ́ṣà ń sápamọ́ sí.” Àwọn afọ́jú ati àwọn arọ bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ninu Tẹmpili, ó sì wò wọ́n sàn. Nígbà tí àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin rí àwọn ohun ìyanu tí Jesu ṣe, tí wọ́n tún gbọ́ bí àwọn ọmọde ti ń kígbe ninu Tẹmpili pé, “Hosana fún Ọmọ Dafidi,” inú wọn ru. Wọ́n sọ fún un pé, “O kò gbọ́ ohun tí àwọn wọnyi ń wí ni?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo gbọ́. Ẹ kò tíì kà á pé, ‘Lẹ́nu àwọn ọmọ-ọwọ́ ati àwọn ọmọ-ọmú ni ìwọ ti gba ìyìn pípé?’ ” Ó bá fi wọ́n sílẹ̀, ó sì jáde kúrò lọ sí Bẹtani. Níbẹ̀ ni ó gbé sùn. Lówùúrọ̀ ọjọ́ keji, bí ó ti ń pada lọ sinu ìlú, ebi ń pa á. Bí ó ti rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan lọ́nà, ó yà lọ sí ìdí rẹ̀, ṣugbọn, kò rí nǹkankan lórí rẹ̀ àfi kìkì ewé. Ó bá sọ fún un pé, “O kò ní so mọ́ laelae.” Lẹsẹkẹsẹ ni igi ọ̀pọ̀tọ́ náà bá gbẹ! Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i, ẹnu yà wọ́n. Wọ́n ń sọ pé, “Báwo ni igi ọ̀pọ̀tọ́ náà ṣe gbẹ lẹsẹkẹsẹ.” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, bí ẹ bá ní igbagbọ, láì ṣiyèméjì, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí nìkan kọ́ ni ẹ óo ṣe, ṣugbọn bí ẹ bá sọ fún òkè yìí pé, ‘Dìde, kí o lọ rì sinu òkun,’ bẹ́ẹ̀ ni yóo rí. Ohunkohun tí ẹ bá bèèrè ninu adura, bí ẹ bá gbàgbọ́, ẹ óo rí i gbà.” Nígbà tí Jesu dé inú Tẹmpili, bí ó ti ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́, àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbààgbà ìlú wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, “Irú agbára wo ni o fi ń ṣe nǹkan wọnyi? Ta ni ó sì fún ọ ní agbára náà?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi náà yóo bi yín léèrè ọ̀rọ̀ kan. Tí ẹ bá dá mi lóhùn, èmi náà yóo wá sọ irú agbára tí mo fi ń ṣe nǹkan wọnyi. Ìrìbọmi tí Johanu ń ṣe, báwo ló ti jẹ́: ṣé láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá ni tabi láti ọ̀dọ̀ eniyan?” Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn jiyàn, wọ́n ń wí pé, “Bí a bá sọ pé, ‘Láti ọ̀run ni,’ yóo bi wá pé, ‘Kí ló dé tí ẹ kò fi gbà á gbọ́?’ Bí a bá sì wí pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ eniyan ni,’ a bẹ̀rù àwọn eniyan, nítorí gbogbo eniyan gbà pé wolii tòótọ́ ni Johanu.” Wọ́n bá dá Jesu lóhùn pé, “Àwa kò mọ̀.” Ó bá sọ fún wọn pé, “Èmi náà kò ní sọ irú àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọnyi fun yín.” Ó wá bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ rò nípa èyí? Ọkunrin kan ní ọmọ meji. Ó lọ sọ́dọ̀ ekinni, ó sọ fún un pé, ‘Ọmọ, lọ ṣiṣẹ́ ninu ọgbà àjàrà mi lónìí.’ Ọmọ náà dá a lóhùn pé, ‘N kò ní lọ.’ Ṣugbọn lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ó ronupiwada, ó bá lọ. Ọkunrin náà lọ sọ́dọ̀ ọmọ keji, ó sọ fún un bí ó ti sọ fún ekinni. Ọmọ náà dá a lóhùn pé, ‘Ó dára, mo gbọ́, Baba!’ Ṣugbọn kò lọ. Ninu àwọn mejeeji, èwo ni ó ṣe ìfẹ́ baba rẹ̀?” Wọ́n ní, “Ekinni ni.” Jesu bá sọ fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé àwọn agbowó-odè ati àwọn aṣẹ́wó yóo ṣáájú yín wọ ìjọba Ọlọrun. Nítorí Johanu wá sọ́dọ̀ yín ní ọ̀nà òdodo, ṣugbọn ẹ kò gbà á gbọ́. Ṣugbọn àwọn agbowó-odè ati àwọn aṣẹ́wó gbà á gbọ́. Lẹ́yìn tí ẹ rí èyí, ẹ kò ronupiwada kí ẹ gbà á gbọ́.” Jesu ní, “Ẹ tún gbọ́ òwe mìíràn. Baba kan wà tí ó gbin èso àjàrà sí oko rẹ̀. Ó ṣe ọgbà yí i ká; ó wa ilẹ̀ ìfúntí sibẹ; ó kọ́ ilé-ìṣọ́ sí i; ó bá fi í lé àwọn alágbàro lọ́wọ́, ó lọ sí ìdálẹ̀. Nígbà tí ó tó àkókò ìkórè, ó rán àwọn ẹrú rẹ̀ sí àwọn alágbàro náà láti gba ìpín tirẹ̀ wá ninu èso rẹ̀. Ṣugbọn àwọn alágbàro náà mú àwọn ẹrú rẹ̀, wọ́n na àwọn kan, wọ́n pa àwọn kan, wọ́n sọ àwọn mìíràn ní òkúta. Sibẹ ó tún rán àwọn ẹrú mìíràn tí wọ́n pọ̀ ju àwọn ti àkọ́kọ́ lọ; ṣugbọn bákan náà ni àwọn alágbàro yìí ṣe sí wọn. Ní ìgbẹ̀yìn ó wá rán ọmọ rẹ̀ sí wọn, ó ní, ‘Wọn óo bu ọlá fún ọmọ mi.’ Ṣugbọn nígbà tí àwọn alágbàro náà rí ọmọ rẹ̀, wọ́n wí láàrin ara wọn pé, ‘Àrólé rẹ̀ ni èyí. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á pa á, kí ogún rẹ̀ lè di tiwa.’ Wọ́n bá mú un, wọ́n tì í jáde kúrò ninu ọgbà àjàrà, wọ́n sì pa á. “Nítorí náà, nígbà tí ẹni tí ó ni ọgbà àjàrà bá dé, kí ni yóo ṣe sí àwọn alágbàro náà?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Pípa ni yóo pa àwọn olubi náà, yóo fi ọgbà àjàrà rẹ̀ lé àwọn alágbàro mìíràn lọ́wọ́, tí yóo fún un ní èso ní àkókò tí ó wọ̀.” Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ kò ì tíì kà ninu Ìwé Mímọ́ pé, ‘Òkúta tí àwọn tí ń mọlé kọ̀ sílẹ̀, òun ni ó di pataki ní igun ilé. Iṣẹ́ Oluwa ni èyí, ìyanu ni ó jẹ́ lójú wa.’ “Nítorí èyí mo sọ fun yín pé a gba ìjọba Ọlọrun lọ́wọ́ yín, a fi fún orílẹ̀-èdè tí yóo so èso tí ó yẹ. [ Bí eniyan bá kọlu òkúta yìí, olúwarẹ̀ yóo rún wómúwómú. Bí òkúta yìí bá bọ́ lu eniyan, yóo rẹ́ olúwarẹ̀ pẹ́tẹ́pẹ́tẹ́.”] Nígbà tí àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi gbọ́ àwọn òwe wọnyi, wọ́n mọ̀ pé àwọn ni ó ń bá wí. Wọ́n bá ń wá ọ̀nà láti mú un, ṣugbọn wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan, nítorí àwọn eniyan gbà á bíi wolii. Jesu tún fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀. Ó ní, “Ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan, tí ó ń gbeyawo fún ọmọ rẹ̀. Ó rán àwọn ẹrú rẹ̀ lọ pe àwọn tí ó dájọ́ igbeyawo náà fún, ṣugbọn wọn kò fẹ́ wá. Ó tún rán àwọn ẹrú mìíràn, kí wọ́n sọ fún àwọn tí a ti pè pé, ‘Mo ti se àsè tán; mo ti pa mààlúù ati àwọn ẹran ọlọ́ràá; mo ti ṣe ètò gbogbo tán. Ẹ wá sí ibi igbeyawo.’ Ṣugbọn wọn kò bìkítà. Ọ̀kan lọ sí oko rẹ̀, òmíràn lọ sí ìdí òwò rẹ̀. Àwọn ìyókù ki àwọn ẹrú mọ́lẹ̀, wọ́n lù wọ́n pa. Inú wá bí ọba náà, ó bá rán àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ kí wọ́n pa àwọn apànìyàn wọ̀n-ọn-nì run, kí wọ́n sì dáná sun ìlú wọn. Ó bá sọ fún àwọn ẹrú rẹ̀ pé, ‘A ti parí gbogbo ètò igbeyawo, ṣugbọn àwọn tí a ti pè kò yẹ. Ẹ wá lọ sí gbogbo oríta ìlú, ẹ pe gbogbo ẹni tí ẹ bá rí wá sí ibi igbeyawo.’ Àwọn ẹrú náà bá lọ sí ìgboro, wọ́n kó gbogbo àwọn tí wọ́n rí wá, ati àwọn eniyan rere, ati àwọn eniyan burúkú. Oniruuru eniyan bá kún ibi àsè igbeyawo. “Nígbà tí ọba wọlé láti wo àwọn tí wọn ń jẹun, ó rí ọkunrin kan níbẹ̀ tí kò wọ aṣọ igbeyawo. Ọba bi í pé, ‘Arakunrin, báwo ni o ti ṣe wọ ìhín láì ní aṣọ igbeyawo?’ Ṣugbọn kẹ́kẹ́ pamọ́ ọkunrin náà lẹ́nu. Ọba bá pàṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, ‘Ẹ dì í tọwọ́-tẹsẹ̀, kí ẹ sọ ọ́ sinu òkùnkùn biribiri. Níbẹ̀ ni ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà.’ “Nítorí ọpọlọpọ ni a pè, ṣugbọn àwọn díẹ̀ ni a yàn.” Àwọn Farisi bá lọ forí-korí wọ́n ń wá ọ̀nà tí wọn yóo fi ká ọ̀rọ̀ mọ́ Jesu lẹ́nu. Wọ́n bá rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wọn pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Hẹrọdu láti bi í pé, “Olùkọ́ni, a mọ̀ pé olóòótọ́ ni ọ́, ati pé pẹlu òtítọ́ ni o fi ń kọ́ eniyan ní ọ̀nà Ọlọrun; o kì í ṣe ojuṣaaju fún ẹnikẹ́ni nítorí o kì í wojú eniyan kí o tó sọ̀rọ̀. Nítorí náà sọ ohun tí o rò fún wa. Ó tọ̀nà láti san owó-orí fún Kesari ni, àbí kò tọ̀nà?” Ṣugbọn Jesu mọ èrò ibi tí ó wà lọ́kàn wọn. Ó ní, “Kí ló dé tí ẹ fi ń dẹ mí ẹ̀yin alárèékérekè yìí? Ẹ fi owó tí ẹ fi ń san owó-orí hàn mí.” Wọ́n bá mú owó fadaka kan fún un. Ó wá bi wọ́n pé, “Àwòrán ati àkọlé ta ni èyí?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ti Kesari ni.” Ó bá sọ fún wọn pé, “Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ fi ohun tí ó jẹ́ ti Kesari fún Kesari, kí ẹ sì fi ohun tíí ṣe ti Ọlọrun fún Ọlọrun.” Nígbà tí wọ́n gbọ́ báyìí, ẹnu yà wọ́n, wọ́n bá fi í sílẹ̀, wọ́n sì bá tiwọn lọ. Ní ọjọ́ náà, àwọn Sadusi kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀. (Àwọn Sadusi ni wọ́n sọ pé kò sí ajinde.) Wọ́n bi í pé, “Olùkọ́ni, Mose sọ pé bí ẹnìkan bá kú láì ní ọmọ, kí àbúrò rẹ̀ fẹ́ aya rẹ̀ kí ó lè bí ọmọ fún ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò meje kan wà lọ́dọ̀ wa. Ekinni gbé iyawo, láìpẹ́ ó kú. Nígbà tí kò bí ọmọ, ó fi iyawo rẹ̀ sílẹ̀ fún àbúrò rẹ̀. Ekeji náà kú, ati ẹkẹta, títí tí àwọn mejeeje fi kú. Ní ìkẹyìn gbogbo wọn, obinrin náà wá kú. Tí ó bá di àkókò ajinde, ninu àwọn mejeeje, iyawo ta ni obinrin náà yóo jẹ́, nígbà tí ó jẹ́ pé gbogbo wọn ni wọ́n ti fi ṣe aya?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ṣìnà, nítorí pé ẹ kò mọ Ìwé Mímọ́ ati agbára Ọlọrun. Nítorí pé ní àkókò ajinde kò ní sí pé à ń gbé iyawo, tabi pé à ń fi ọmọ fún ọkọ; nítorí bí àwọn angẹli ti rí ní ọ̀run ni wọn yóo rí. Nípa ti ajinde àwọn òkú, ẹ kò ì tíì ka ọ̀rọ̀ tí Ọlọrun sọ fun yín pé, ‘Èmi ni Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu.’ Ọlọrun kì í ṣe Ọlọrun àwọn òkú, Ọlọrun àwọn alààyè ni.” Nígbà tí àwọn eniyan gbọ́, ẹnu yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ̀. Nígbà tí àwọn Farisi gbọ́ pé ó ti pa àwọn Sadusi lẹ́nu mọ́, wọ́n kó ara wọn jọ. Ọ̀kan ninu wọn tí ó jẹ́ amòfin, bi í ní ìbéèrè kan láti fi dẹ ẹ́, pé, “Olùkọ́ni, òfin wo ni ó ṣe pataki jùlọ ninu Ìwé Òfin?” Jesu dá a lóhùn pé, “ ‘Fẹ́ Oluwa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo ẹ̀mí rẹ, ati ní gbogbo èrò rẹ.’ Èyí ni òfin tí ó ga jùlọ, òun sì ni ekinni. Ekeji fi ara jọ ọ́: ‘Fẹ́ràn ọmọnikeji rẹ bí o ti fẹ́ ara rẹ.’ Òfin mejeeji wọnyi ni gbogbo òfin ìyókù ati ọ̀rọ̀ inú ìwé àwọn wolii rọ̀ mọ́.” Nígbà tí àwọn Farisi péjọ pọ̀, Jesu bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ rò nípa Mesaya, ọmọ ta ni?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ọmọ Dafidi ni.” Ó bá tún bi wọ́n pé, “Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, báwo ni Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe darí Dafidi tí Dafidi fi pe Mesaya ní ‘Oluwa’? Dafidi sọ pé, ‘OLUWA sọ fún Oluwa mi pé: Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi títí n óo fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di ohun ìtìsẹ̀ rẹ.’ Bí Dafidi bá pè é ní ‘OLUWA’, báwo ni Mesaya ti ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀?” Kò sí ẹnìkan tí ó lè dá a lóhùn ọ̀rọ̀ yìí. Láti ọjọ́ náà, ẹnikẹ́ni kò ní ìgboyà láti tún bi í ní ohunkohun mọ́. Jesu bá sọ fún àwọn eniyan ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Àwọn amòfin ati àwọn Farisi ni olùtúmọ̀ òfin Mose. Nítorí náà, ohun gbogbo tí wọ́n bá sọ fun yín ni kí ẹ ṣe. Ṣugbọn ẹ má ṣe tẹ̀lé ìwà wọn, nítorí ọ̀tọ̀ ni ohun tí wọn óo sọ, ọ̀tọ̀ ni ohun tí wọn óo ṣe. Wọn á di ẹrù wúwo, wọn á gbé e ka àwọn eniyan lórí, bẹ́ẹ̀ ni àwọn fúnra wọn kò sì jẹ́ fi ọwọ́ wọn kan ẹrù náà. Gbogbo ohun tí wọn ń ṣe, wọ́n ń ṣe é kí eniyan lè rí wọn ni. Wọn á di tírà pàlàbà-pàlàbà mọ́ iwájú. Wọn á ṣe waja-waja ńláńlá sí etí aṣọ wọn. Wọ́n fẹ́ràn ìjókòó ọlá níbi àsè. Wọ́n fẹ́ràn àga iwájú ní ilé ìpàdé. Wọ́n fẹ́ràn kí eniyan máa kí wọn láàrin ọjà ati kí àwọn eniyan máa pè wọ́n ní ‘Olùkọ́ni.’ Ṣugbọn ẹ̀yin ní tiyín, ẹ má jẹ́ kí wọ́n pè yín ní ‘Olùkọ́ni,’ nítorí ẹnìkan ṣoṣo ni olùkọ́ni yín; arakunrin ni gbogbo yín jẹ́. Ẹ má pe ẹnìkan ní ‘Baba’ ní ayé, nítorí ẹnìkan ṣoṣo ni Baba yín, ẹni tí ó wà ní ọ̀run. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni pè yín ní ‘Ọ̀gá,’ nítorí ọ̀gá kanṣoṣo ni ẹ ní, òun ni Mesaya. Ẹni tí ó bá lọ́lá jùlọ láàrin yín ni kí ó ṣe iranṣẹ yín. Ẹni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a óo rẹ̀ sílẹ̀; ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óo gbé ga. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin alárèékérekè wọnyi. Nítorí ẹ ti ìlẹ̀kùn ìjọba ọ̀run mọ́ àwọn eniyan, ẹ̀yin fúnra yín kò wọlé, bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí wọ́n fẹ́ wọlé, ẹ kò jẹ́ kí wọ́n wọlé. [ “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati Farisi, alaiṣootọ; nítorí ẹ̀ ń jẹ ilé àwọn opó run; ẹ̀ ń fi adura gígùn ṣe ìbòjú. Nítorí èyí, ẹ óo gba ìdálẹ́bi pupọ.”] “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin aláṣehàn, nítorí ẹ̀ ń la òkun ati oríṣìíríṣìí ìlú kọjá láti mú ẹyọ ẹnìkan láti orílẹ̀-èdè mìíràn wọ ẹ̀sìn yín. Nígbà tí ó bá ti wọ ẹ̀sìn tán, ẹ wá sọ ọ́ di ẹni ọ̀run àpáàdì ní ìlọ́po meji ju ẹ̀yin alára lọ. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin afọ́jú tí ń fọ̀nà han eniyan. Ẹ̀ ń sọ pé, ‘Bí eniyan bá fi Tẹmpili búra, kò ṣe nǹkankan. Ṣugbọn bí eniyan bá fi wúrà tí ó wà ninu Tẹmpili búra, olúwarẹ̀ níláti mú ìbúra rẹ̀ ṣẹ.’ Ẹ̀yin afọ́jú òmùgọ̀ wọnyi! Èwo ni ó ṣe pataki jù! Wúrà ni tabi Tẹmpili tí a fi sọ wúrà di ohun ìyàsọ́tọ̀? Ẹ tún sọ pé, ‘Bí eniyan bá fi pẹpẹ ìrúbọ búra, kò ṣe nǹkankan. Ṣugbọn bí eniyan bá fi ọrẹ tí ó wà lórí pẹpẹ ìrúbọ búra, olúwarẹ̀ níláti mú ìbúra rẹ̀ ṣẹ.’ Ẹ̀yin afọ́jú wọnyi! Èwo ni ó ṣe pataki jù, ọrẹ ni, tabi pẹpẹ ìrúbọ tí ó sọ ọ́ di ohun ìyàsọ́tọ̀? Nítorí náà ẹni tí ó bá fi pẹpẹ ìrúbọ búra, ati pẹpẹ ati ohun gbogbo tí ó wà lórí rẹ̀ ni ó fi búra. Ẹni tí ó bá fi Tẹmpili búra, ohun tí ó wà ninu rẹ̀ ati Ọlọrun tí ó ń gbé inú rẹ̀ ni ó fi búra pẹlu. Ẹni tí ó bá fi ọ̀run búra, ó fi ìtẹ́ Ọlọrun ati Ọlọrun tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà búra pẹlu. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin aláṣehàn wọnyi! Ẹ̀ ń san ìdámẹ́wàá àwọn èròjà ọbẹ̀ tí wọ́n jẹ́ eléwé, nígbà tí ẹ gbàgbé àwọn ohun tí ó ṣe pataki ninu òfin: bíi ìdájọ́ òdodo, àánú, ati igbagbọ. Àwọn ohun tí ẹ̀ bá mójútó nìyí, láì gbàgbé ìdámẹ́wàá. Ẹ̀yin afọ́jú tí ń fọ̀nà han eniyan! Ẹ̀ ń yọ kòkòrò tín-tìn-tín kúrò ninu ohun tí ẹ̀ ń mu, ṣugbọn ẹ̀ ń gbé ràkúnmí mì mọ́ omi yín! “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin aláṣehàn. Ẹ̀ ń fọ òde ife ati òde àwo oúnjẹ nígbà tí inú wọn kún fún àwọn ohun tí ẹ fi ìwà olè ati ìwà ìmọ-tara-ẹni-nìkan já gbà. Ìwọ afọ́jú Farisi! Kọ́kọ́ fọ inú ife ná, òde rẹ̀ náà yóo sì mọ́. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin aláṣehàn wọnyi. Ẹ dàbí àwọn ibojì tí a kùn ní funfun, tí ó dùn-ún wò lóde, ṣugbọn inú wọn kún fún egungun òkú ati oríṣìíríṣìí ohun ẹ̀gbin. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ẹ̀yin náà rí lóde, lójú àwọn eniyan ẹ dàbí ẹni rere, ṣugbọn ẹ kún fún àṣehàn ati ìwà burúkú. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin aláṣehàn wọnyi. Ẹ̀ ń ṣe ibojì fún àwọn wolii, ẹ sì ń ṣe ibojì àwọn eniyan rere lọ́ṣọ̀ọ́. Ẹ wá ń sọ pé, ‘Bí ó bá jẹ́ pé a wà ní ìgbà àwọn baba wa, àwa kò bá tí lọ́wọ́ ninu ikú àwọn wolii.’ Nípa gbolohun yìí, ẹ̀ ń jẹ́rìí sí ara yín pé ọmọ àwọn tí ó pa àwọn wolii ni yín. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin náà ẹ múra, kí ẹ parí ohun tí àwọn baba yín ṣe kù! Ẹ̀yin ejò, ìran paramọ́lẹ̀! Báwo ni ẹ kò ti ṣe ní gba ìdájọ́ ọ̀run àpáàdì? Nítorí èyí ni mo fi rán àwọn wolii, àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ati àwọn amòfin si yín. Ẹ óo pa òmíràn ninu wọn, ẹ óo sì kan òmíràn mọ́ agbelebu. Ẹ óo na àwọn mìíràn ninu wọn ní ilé ìpàdé yín, ẹ óo sì máa lépa wọn láti ìlú dé ìlú. Ẹ óo ṣe gbogbo nǹkan wọnyi kí ẹ lè fi orí gba ẹ̀bi ikú gbogbo eniyan rere tí ẹ ti ta ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀; ohun tí ó ṣẹ̀ láti orí Abeli, ẹni rere títí fi dé orí Sakaraya, ọmọ Berekaya, tí ẹ pa láàrin àgọ́ mímọ́ ati pẹpẹ ìrúbọ. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ìran yìí ni yóo fi orí fá gbogbo ẹ̀bi yìí. “Jerusalẹmu! Jerusalẹmu! Ìwọ tí ò ń pa àwọn wolii, tí ò ń sọ àwọn tí a rán sí ọ ní òkúta pa! Ìgbà mélòó ni mo ti fẹ́ kó àwọn ọmọ rẹ jọ, bí adìẹ tí ń kó àwọn ọmọ rẹ̀ sí abẹ́! Ṣugbọn o kọ̀ fún mi. Wò ó, a óo sọ Tẹmpili rẹ di ahoro. Nítorí náà, mo sọ fun yín pé ẹ kò ní fojú kàn mí mọ́ títí di àkókò tí ẹ óo wí pé, ‘Olùbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ Oluwa!’ ” Jesu jáde kúrò ninu Tẹmpili. Bí ó ti ń lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá, wọ́n pe akiyesi rẹ̀ sí bí a ti ṣe kọ́ ilé náà. Ó sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí gbogbo ilé yìí, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé kò ní ku òkúta kan lórí ekeji tí wọn kò ní wó palẹ̀.” Nígbà tí Jesu jókòó lórí Òkè Olifi, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bi í pé, “Sọ fún wa, nígbà wo ni gbogbo èyí yóo ṣẹlẹ̀, kí sì ni àmì àkókò wíwá rẹ ati ti òpin ayé?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má baà tàn yín jẹ. Nítorí ọ̀pọ̀ ni yóo wá ní orúkọ mi, tí wọn yóo máa sọ pé, ‘Èmi gan-an ni Mesaya náà,’ wọn yóo sì tan ọpọlọpọ jẹ. Àkókò ń bọ̀ tí ẹ óo gbúròó ogun ati ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ogun. Ẹ má bẹ̀rù. Èyí níláti rí bẹ́ẹ̀, ṣugbọn kò ì tíì tó àkókò tí òpin ayé yóo dé. Nítorí orílẹ̀-èdè yóo dìde sí orílẹ̀-èdè; ìjọba yóo dìde sí ìjọba. Ìyàn yóo mú. Ilẹ̀ yóo máa mì ní ọpọlọpọ ìlú. Ìbẹ̀rẹ̀ ìrora bíi ti ìrọbí ni gbogbo èyí. “Ní àkókò náà, wọn yóo fà yín lé àwọn eniyan lọ́wọ́ pé kí wọ́n jẹ yín níyà, kí wọ́n sì pa yín. Gbogbo ará ayé ni yóo kórìíra yín nítorí orúkọ mi. Ọpọlọpọ yóo kùnà ninu igbagbọ; wọn yóo tú àwọn mìíràn fó; wọn yóo sì kórìíra àwọn mìíràn. Ọpọlọpọ àwọn wolii èké ni yóo dìde, wọn yóo tan ọpọlọpọ jẹ. Nítorí pé ìwà ìbàjẹ́ yóo gbilẹ̀, ìfẹ́ ọpọlọpọ yóo rẹ̀wẹ̀sì. Ṣugbọn ẹni tí ó bá forí tì í títí dé òpin, òun ni a óo gbà là. A óo waasu ìyìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ayé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí sí gbogbo orílẹ̀-èdè. Lẹ́yìn náà ni òpin yóo dé. “Nígbà náà ni ẹ óo rí ohun ẹ̀gbin tí wolii Daniẹli ti sọ tẹ́lẹ̀, tí ó dúró ní ibi mímọ́ (ìwọ olùkàwé yìí, jẹ́ kí ohun tí ò ń kà yé ọ). Tí èyí bá ti ṣẹlẹ̀, kí àwọn tí ó wà ní Judia sálọ sí orí òkè. Ẹni tí ó wà lókè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì kò gbọdọ̀ sọ̀kalẹ̀ wọlé lọ mú àwọn ohun ìní rẹ̀. Ẹni tí ó bá wà lóko kò gbọdọ̀ pada sẹ́yìn láti lọ mú ẹ̀wù rẹ̀ tí ó bọ́ sílẹ̀. Ó ṣe! Fún àwọn aboyún ati fún àwọn tí wọn bá ń tọ́ ọmọ lọ́wọ́ ní ọjọ́ náà. Ẹ gbadura pé kí sísá yín má bọ́ sí ìgbà òtútù nini, tabi sí Ọjọ́ Ìsinmi. Nítorí ìpọ́njú yóo pọ̀ ní àkókò náà, irú èyí tí kò sí rí láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyìí; irú rẹ̀ kò sì tún ní sí mọ́. Bí Ọlọrun kò bá dín àwọn ọjọ́ náà kù ni, ẹ̀dá kankan kì bá tí là. Ṣugbọn nítorí àwọn àyànfẹ́, Ọlọrun yóo dín àwọn ọjọ́ náà kù. “Ní àkókò náà, bí ẹnìkan bá sọ fun yín pé, ‘Wò ó! Mesaya náà nìyí níhìn-ín!’ Tabi ‘Wò ó! Mesaya ló wà lọ́hùn-ún nì!’ ẹ má ṣe gbàgbọ́. Nítorí àwọn Mesaya èké ati àwọn wolii èké yóo dìde. Wọn yóo fi àmì ńlá hàn, wọn yóo sì ṣe iṣẹ́ ìyanu láti tan eniyan jẹ; bí ó bá ṣeéṣe fún wọn, wọn óo tan àwọn àyànfẹ́ pàápàá jẹ. Ẹ wò ó, ogun àsọtẹ́lẹ̀ nìyí. “Nítorí náà, bí wọn bá sọ fun yín pé, ‘Ẹ wá wò ó ní aṣálẹ̀,’ ẹ má lọ. Tabi tí wọ́n bá sọ pé, ‘Ẹ wá wò ó ní ìyẹ̀wù,’ ẹ má ṣe gbàgbọ́. Nítorí bí mànàmáná ti ń kọ ní ìlà oòrùn, tí ó sì ń mọ́lẹ̀ dé ìwọ̀ oòrùn, bẹ́ẹ̀ gan-an ni dídé Ọmọ-Eniyan yóo rí. “Níbi tí òkú ẹran bá wà, níbẹ̀ ni àwọn gúnnugún yóo péjọ sí. “Lẹsẹkẹsẹ lẹ́yìn ìpọ́njú ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, oòrùn yóo ṣókùnkùn, òṣùpá kò ní tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀, àwọn ìràwọ̀ yóo jábọ́ láti ọ̀run. Gbogbo àwọn agbára tí ó wà ní ọ̀run ni a óo mì jìgìjìgì. Àmì Ọmọ-Eniyan yóo wá yọ ní ọ̀run. Gbogbo àwọn ẹ̀yà ayé yóo figbe ta, wọn yóo rí Ọmọ-Eniyan tí ó ń bọ̀ lórí ìkùukùu ní ọ̀run pẹlu agbára ògo ńlá. Yóo wá rán angẹli rẹ̀ pẹlu fèrè ńlá, wọn yóo kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jọ láti igun mẹrẹẹrin ayé; àní láti ìkangun ọ̀run kan dé ìkangun keji. “Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ lára igi ọ̀pọ̀tọ́. Nígbà tí ẹ̀ka rẹ̀ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ, tí ó bá bẹ̀rẹ̀ sí rúwé, ẹ mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn súnmọ́ tòsí. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni, nígbà tí ẹ bá rí gbogbo nǹkan wọnyi, kí ẹ̀yin náà mọ̀ pé àkókò súnmọ́ tòsí, ó ti dé ẹnu ọ̀nà. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé àwọn eniyan ìran yìí kò ní tíì kú tán títí gbogbo nǹkan wọnyi yóo fi ṣẹlẹ̀. Ọ̀run ati ayé yóo kọjá lọ ṣugbọn ọ̀rọ̀ mi kò ní kọjá lọ. “Kò sí ẹni tí ó mọ ọjọ́ náà ati wakati náà. Àwọn angẹli ọ̀run kò mọ̀ ọ́n; ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, àfi Baba nìkan ni ó mọ̀ ọ́n. Nítorí bí ó ti rí ní ìgbà Noa, bẹ́ẹ̀ ni àkókò dídé Ọmọ-Eniyan yóo rí. Nítorí ní àkókò náà, kí ìkún-omi tó dé, ńṣe ni wọ́n ń jẹ, tí wọn ń mu, wọ́n ń gbé iyawo, wọ́n ń fi ọmọ fọ́kọ, títí ó fi di ọjọ́ tí Noa wọ inú ọkọ̀. Wọn kò fura títí ìkún-omi fi dé, tí ó gba gbogbo wọn lọ. Bẹ́ẹ̀ ni àkókò dídé Ọmọ-Eniyan yóo rí. Àwọn meji yóo wà ní oko, a óo mú ọ̀kan, a óo fi ekeji sílẹ̀. Àwọn obinrin meji yóo máa lọ ọkà ninu ilé ìlọkà. A óo mú ọ̀kan, a óo fi ekeji sílẹ̀. “Nítorí náà, ẹ máa ṣọ́nà, nítorí ẹ kò mọ ọjọ́ tí Oluwa yín ń bọ̀. Ẹ mọ èyí pé bí baálé bá mọ àsìkò tí olè yóo dé, ìbá máa ṣọ́nà, kì bá tí jẹ́ kí olè kó ilé rẹ̀. Nítorí náà, kí ẹ̀yin náà wà ní ìmúrasílẹ̀, nítorí ní wakati tí ẹ kò rò tẹ́lẹ̀ ni Ọmọ-Eniyan yóo dé. “Bí ẹrú kan bá jẹ́ olóòótọ́ ati ọlọ́gbọ́n, ọ̀gá rẹ̀ á fi ilé rẹ̀ lé e lọ́wọ́, pé kí ó máa fún àwọn eniyan ní oúnjẹ lásìkò. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹrú náà tí ọ̀gá rẹ̀ bá bá a lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé yóo fi í ṣe olùtọ́jú ohun gbogbo tí ó ní. Ṣugbọn bí ẹrú bá jẹ́ olubi, tí ó bá rò ní ọkàn rẹ̀ pé, ‘Ọ̀gá mi kò ní tètè dé!’ Tí ó wá bẹ̀rẹ̀ sí lu àwọn ẹrú, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí ó ń jẹ, tí ó ń mu pẹlu àwọn ọ̀mùtí, ọ̀gá ẹrú náà yóo dé ní ọjọ́ tí kò rò, ati ní wakati tí kò lérò. Ọ̀gá rẹ̀ yóo wá nà án, yóo fi í sí ààrin àwọn alaiṣootọ. Níbẹ̀ ni yóo máa gbé sunkún tí yóo sì máa payínkeke. “Ní àkókò náà, ọ̀rọ̀ ìjọba ọ̀run yóo dàbí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn wundia mẹ́wàá, tí wọn gbé àtùpà wọn láti jáde lọ pàdé ọkọ iyawo. Marun-un ninu wọn jẹ́ òmùgọ̀, marun-un sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Àwọn òmùgọ̀ gbé àtùpà, ṣugbọn wọn kò gbé epo lọ́wọ́. Àwọn ọlọ́gbọ́n rọ epo sinu ìgò, wọ́n gbé e lọ́wọ́ pẹlu àtùpà wọn. Nígbà tí ọkọ iyawo pẹ́ kí ó tó dé, gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí tòògbé, wọ́n bá sùn lọ. “Nígbà tí ó di ààrin ọ̀gànjọ́, igbe ta pé, ‘Ọkọ iyawo dé! Ẹ jáde lọ pàdé rẹ̀.’ Nígbà náà ni gbogbo àwọn wundia náà tají, wọ́n tún iná àtùpà wọn ṣe. Àwọn wundia òmùgọ̀ wá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ àwọn ọlọ́gbọ́n pé, ‘Ẹ jọ̀wọ́ ẹ fún wa ninu epo yín, nítorí àtùpà wa ń kú lọ.’ Àwọn ọlọ́gbọ́n dá wọn lóhùn pé, ‘Rárá o! Epo tí a ní kò tó fún àwa ati ẹ̀yin. Ẹ kúkú lọ sọ́dọ̀ àwọn tí ń ta epo, kí ẹ ra tiyín.’ Nígbà tí wọ́n lọ ra epo, ọkọ iyawo dé, àwọn tí wọ́n ti múra sílẹ̀ bá wọ ilé ibi igbeyawo pẹlu rẹ̀, wọ́n sì ti ìlẹ̀kùn. “Ní ìgbẹ̀yìn àwọn wundia yòókù dé, wọ́n ní, ‘Alàgbà, alàgbà, ẹ ṣílẹ̀kùn fún wa!’ Ṣugbọn ó dá wọn lóhùn pé, ‘Rárá o! Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé èmi kò mọ̀ yín.’ “Nítorí náà, ẹ máa ṣọ́nà, nítorí ẹ kò mọ ọjọ́ tabi àkókò. “Nígbà náà ìjọba ọ̀run yóo tún rí báyìí. Ọkunrin kan ń lọ sí ìdálẹ̀. Ó bá pe àwọn ẹrú rẹ̀, ó fi àwọn dúkìá rẹ̀ lé wọn lọ́wọ́. Ó fún ọ̀kan ni àpò owó marun-un, ó fún ekeji ní àpò meji, ó fún ẹkẹta ní àpò kan. Ó fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn bí agbára rẹ̀ ti tó; ó bá lọ sí ìdálẹ̀. Kíá, bí ó ti lọ tán, ẹni tí ó gba àpò marun-un lọ ṣòwò, ó bá jèrè àpò marun-un. Bákan náà ni ẹni tí ó gba àpò meji. Òun náà jèrè àpò meji. Ṣugbọn ẹni tí ó gba àpò kan lọ wa ilẹ̀, ó bá bo owó oluwa rẹ̀ mọ́lẹ̀. “Lẹ́yìn ọjọ́ pípẹ́, oluwa àwọn ẹrú náà dé, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí bi wọ́n bí wọ́n ti ṣe sí. Nígbà tí ẹni tí ó gba àpò marun-un dé, ó gbé àpò marun-un mìíràn wá, ó ní, ‘Alàgbà, àpò marun-un ni o fún mi. Mo ti jèrè àpò marun-un lórí rẹ̀.’ Oluwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘O ṣeun, ìwọ olóòótọ́ ẹrú, eniyan rere ni ọ́. O ti ṣe olóòótọ́ ninu nǹkan kékeré, a óo fi ọ́ ṣe alámòójútó nǹkan pupọ. Bọ́ sinu ayọ̀ oluwa rẹ.’ “Bẹ́ẹ̀ náà ni ẹni tí ó gba àpò meji wá, ó ní ‘Alàgbà, àpò meji ni o fún mi. Mo ti jèrè àpò meji lórí rẹ̀!’ Oluwa rẹ̀ sọ fún un pé, ‘O ṣeun, ìwọ olóòótọ́ ẹrú, eniyan rere ni ọ́. O ti ṣe olóòótọ́ ninu nǹkan kékeré, n óo fi ọ́ ṣe alámòójútó nǹkan pupọ. Bọ́ sinu ayọ̀ oluwa rẹ.’ “Lẹ́yìn náà, ẹni tí ó gba àpò kan wá, ó ní, ‘Alàgbà mo mọ̀ pé eniyan líle ni ọ́. Ibi tí o kò fúnrúgbìn sí ni o tí ń kórè. Ibi tí o kò fi nǹkan pamọ́ sí ni ò ń fojú wá a sí. Ẹ̀rù rẹ bà mí, mo bá lọ fi àpò kan rẹ pamọ́ sinu ilẹ̀. Òun nìyí, gba nǹkan rẹ!’ “Olúwa rẹ̀ dá a lóhùn pé, ‘Ìwọ olubi ati onímẹ̀ẹ́lẹ́ ẹrú yìí. O mọ̀ pé èmi a máa kórè níbi tí n kò fúnrúgbìn sí, ati pé èmi a máa fojú wá nǹkan níbi tí n kò fi pamọ́ sí. Nígbà tí o mọ̀ bẹ́ẹ̀, kí ni kò jẹ́ kí o fi owó mi fún àwọn agbowó-pamọ́ pé nígbà tí mo bá dé, kí n lè gba owó mi pada pẹlu èlé? Nítorí náà, ẹ gba àpò kan náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí ẹ fún ẹni tí ó ní àpò mẹ́wàá. Nítorí ẹni tí ó bá ní, òun ni a óo túbọ̀ fún, kí ó lè ní sí i. Lọ́wọ́ ẹni tí kò ní ni a óo sì ti gba ìwọ̀nba díẹ̀ tí ó ní. Kí ẹ mú ẹrú tí kò wúlò yìí kí ẹ tì í sinu òkùnkùn biribiri. Níbẹ̀ ni ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà.’ “Nígbà tí Ọmọ-Eniyan bá yọ ninu ìgúnwà rẹ̀ pẹlu gbogbo àwọn angẹli, nígbà náà ni yóo jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo péjọ níwájú rẹ̀, yóo wá yà wọ́n sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, bí olùṣọ́-aguntan tíí ya àwọn aguntan sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ewúrẹ́. Yóo fi àwọn olódodo sí ọwọ́ ọ̀tún, yóo fi àwọn ìyókù sí ọwọ́ òsì. Nígbà náà ni ọba yóo sọ fún àwọn ti ọwọ́ ọ̀tún pé, ‘Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bukun. Ẹ wá jogún ìjọba tí a ti pèsè sílẹ̀ fun yín kí á tó dá ayé. Nítorí nígbà tí ebi ń pa mí, ẹ fún mi ní oúnjẹ. Nígbà tí òùngbẹ ń gbẹ mí, ẹ fún mi ní omi mu. Nígbà tí mo jẹ́ àlejò, ẹ gbà mí sílé. Nígbà tí mo wà níhòòhò, ẹ daṣọ bò mí. Nígbà tí mo ṣàìsàn, ẹ wá wò mí. Nígbà tí mo wà lẹ́wọ̀n, ẹ wá sọ́dọ̀ mi.’ “Nígbà náà ni àwọn olódodo yóo dáhùn pé, ‘Oluwa, nígbà wo ni a rí ọ tí ebi ń pa ọ́, tí a fún ọ ní oúnjẹ, tabi tí òùngbẹ ń gbẹ ọ́ tí a fún ọ ní omi mu? Nígbà wo ni a rí ọ níhòòhò tí a daṣọ bò ọ́? Nígbà wo ni a rí ọ tí o ṣàìsàn, tabi tí o wà lẹ́wọ̀n, tí a wá sọ́dọ̀ rẹ?’ Ọba yóo wá dá wọn lóhùn pé, ‘Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti ṣe é fún ọ̀kan ninu àwọn arakunrin mi tí ó kéré jùlọ, èmi ni ẹ ṣe é fún.’ “Nígbà náà ni yóo wá sọ fún àwọn tí ó wà ní ọwọ́ òsì pé, ‘Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin ẹni ègún. Ẹ lọ sinu iná àjóòkú tí a ti pèsè sílẹ̀ fún èṣù ati àwọn angẹli rẹ̀. Nítorí nígbà tí ebi ń pa mí, ẹ kò fún mi ní oúnjẹ jẹ. Òùngbẹ ń gbẹ mí, ẹ kò fún mi ní omi mu. Mo jẹ́ àlejò, ẹ kò gbà mí sílé. Mo wà ní ìhòòhò, ẹ kò daṣọ bò mí. Mo ṣàìsàn, mo wà lẹ́wọ̀n, ẹ kò wá wò mí.’ “Nígbà náà ni àwọn náà yóo bi í pé, ‘Oluwa, nígbà wo ni a rí ọ tí ebi ń pa ọ́, tabi tí òùngbẹ ń gbẹ ọ́, tabi tí o jẹ́ àlejò, tabi tí o wà ní ìhòòhò, tabi tí o ṣàìsàn, tabi tí o wà lẹ́wọ̀n, tí a kò bojútó ọ?’ Yóo wá dá wọn lóhùn pé, ‘Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, níwọ̀n ìgbà tí ẹ kò ti ṣe é fún ọ̀kan ninu àwọn tí ó kéré jùlọ wọnyi, èmi ni ẹ kò ṣe é fún.’ Àwọn wọnyi ni yóo lọ sinu ìyà àìlópin. Ṣugbọn àwọn olódodo yóo wọ ìyè ainipẹkun.” Nígbà tí Jesu parí gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi, ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ mọ̀ pé lẹ́yìn ọjọ́ meji ni Àjọ̀dún Ìrékọjá, a óo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ láti kàn mọ́ agbelebu.” Nígbà náà ni àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ìlú péjọ sí àgbàlá Olórí Alufaa tí ó ń jẹ́ Kayafa. Wọ́n ń gbèrò ọ̀nà bí wọn yóo ti ṣe lè fi ẹ̀tàn mú Jesu kí wọ́n lè pa á. Ṣugbọn wọ́n ń sọ pé, “Kí á má ṣe é ní àkókò àjọ̀dún, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìlú yóo dàrú.” Nígbà tí Jesu wà ní Bẹtani, ninu ilé Simoni tí ó dẹ́tẹ̀ nígbà kan rí, obinrin kan wọlé tọ̀ ọ́ wá tí ó ní ìgò òróró iyebíye olóòórùn dídùn, ni ó bá bẹ̀rẹ̀ sí tú u sí orí Jesu níbi tí ó ti ń jẹun. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu rí i, inú bí wọn. Wọ́n ní, “Kí ni ìdí irú òfò báyìí? Nítorí títà ni à bá ta òróró yìí ní owó iyebíye tí à bá fi fún àwọn talaka.” Jesu mọ ohun tí wọn ń sọ, nítorí náà, ó wí fún wọn pé, “Kí ni ẹ̀ ń da obinrin yìí láàmú sí? Nítorí iṣẹ́ rere ni ó ṣe sí mi lára. Nígbà gbogbo ni ẹ ní àwọn talaka láàrin yín, ṣugbọn ẹ kò ní máa rí mi láàrin yín nígbà gbogbo. Nítorí nígbà tí obinrin yìí da òróró yìí sí mi lára, ó ṣe é fún ìsìnkú mi ni. Mò ń sọ fun yín dájúdájú, níbikíbi tí a bá ń waasu ìyìn rere ní gbogbo ayé, a óo máa sọ nǹkan tí obinrin yìí ṣe ní ìrántí rẹ̀.” Nígbà náà ni ọ̀kan ninu àwọn mejila, tí ó ń jẹ́ Judasi Iskariotu, jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí alufaa. Ó bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ óo fún mi bí mo bá fi Jesu le yín lọ́wọ́?” Wọ́n bá ka ọgbọ̀n owó fadaka fún un. Láti ìgbà náà ni ó ti ń wá ọ̀nà láti fà á lé wọn lọ́wọ́. Ní ọjọ́ kinni Àjọ̀dún Àìwúkàrà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wá sọ́dọ̀ Jesu, wọ́n bi í pé, “Níbo ni o fẹ́ kí á tọ́jú fún ọ láti jẹ àsè Ìrékọjá?” Ó bá dáhùn pé, “Ẹ lọ sí ọ̀dọ̀ ọkunrin kan báyìí nígboro kí ẹ sọ fún un pé, ‘Olùkọ́ni ní: Àkókò mi súnmọ́ tòsí; ní ilé rẹ ni èmi ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi yóo ti jẹ àsè Ìrékọjá.’ ” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà ṣe bí Jesu ti pàṣẹ fún wọn. Wọ́n sì tọ́jú gbogbo nǹkan fún àsè Ìrékọjá. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, ó jókòó láti jẹun pẹlu àwọn mejila. Bí wọ́n ti ń jẹun, ó wí fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ọ̀kan ninu yín yóo fi mí fún àwọn ọ̀tá.” Ọkàn wọn dàrú pupọ; ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ń bèèrè pé, “Kò sá lè jẹ́ èmi ni, Oluwa?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹni tí ó ń fi òkèlè run ọbẹ̀ ninu àwo kan náà pẹlu mi ni ẹni náà tí yóo fi mí fún àwọn ọ̀tá. Ọmọ-Eniyan ń lọ gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí ó fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ gbé! Ìbá sàn fún un bí a kò bá bí i.” Nígbà náà ni Judasi, ẹni tí ó fi í fún àwọn ọ̀tá, bi í pé, “Àbí èmi ni, Olùkọ́ni?” Jesu dá a lóhùn pé, “O ti fi ẹnu ara rẹ sọ ọ́.” Nígbà tí wọn ń jẹun, Jesu mú burẹdi, ó gbadura sí i, ó bù ú, ó bá fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀; ó ní, “Ẹ gbà, ẹ jẹ ẹ́, èyí ni ara mi.” Nígbà tí ó mú ife, ó dúpẹ́, ó fi fún wọn, ó ní “Gbogbo yín ẹ mu ninu rẹ̀. Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi tí a fi dá majẹmu, ẹ̀jẹ̀ tí a ta sílẹ̀ fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ọpọlọpọ eniyan. Mo sọ fun yín, n kò ní mu ọtí èso àjàrà mọ́ títí di ọjọ́ náà tí n óo mu ún pẹlu yín ní ọ̀tun ní ìjọba Baba mi.” Lẹ́yìn náà, wọ́n kọ orin kan, wọ́n bá jáde lọ sórí Òkè Olifi. Nígbà náà Jesu sọ fún wọn pé, “Gbogbo yín ni ẹ óo pada lẹ́yìn mi ní alẹ́ yìí, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Ọwọ́ yóo tẹ olùṣọ́-aguntan, gbogbo agbo aguntan ni a óo fọ́nká!’ “Ṣugbọn lẹ́yìn tí a bá ti jí mi dìde, n óo ṣiwaju yín lọ sí Galili.” Peteru dá a lóhùn pé, “Bí gbogbo àwọn yòókù bá tilẹ̀ pada lẹ́yìn rẹ, bíi tèmi kọ́!” Jesu wí fún un pé, “Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé ní alẹ́ yìí, kí àkùkọ tó kọ, ìwọ yóo sẹ́ mi ní ẹẹmẹta.” Peteru sọ fún un pé, “Bí mo bá tilẹ̀ níláti bá ọ kú, n kò ní sẹ́ ọ.” Bákan náà ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yòókù sọ. Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí ibìkan tí ó ń jẹ́ Gẹtisemani. Ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Ẹ jókòó níhìn-ín, èmi ń lọ gbadura lọ́hùn-ún nì.” Ó bá mú Peteru ati àwọn ọmọ Sebede mejeeji lọ́wọ́, inú rẹ̀ bàjẹ́, ó sì dààmú. Ó wá sọ fún wọn pé, “Mo ní ìbànújẹ́ ọkàn tóbẹ́ẹ̀ tí mo fẹ́rẹ̀ kú. Ẹ dúró níhìn-ín kí ẹ máa bá mi ṣọ́nà.” Ó wá tún lọ siwaju díẹ̀ síi, ó dojúbolẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí gbadura pé, “Baba mi, bí ó bá ṣeéṣe, mú kí ife kíkorò yìí fò mí ru. Ṣugbọn kì í ṣe ohun tí mo fẹ́ ni ṣíṣe, bíkòṣe ohun tí ìwọ fẹ́.” Ó bá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó bá wọn tí wọn ń sùn. Ó sọ fún Peteru pé, “Èyí ni pé ẹ kò lè bá mi ṣọ́nà fún wakati kan? Ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ máa gbadura, kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdánwò. Ẹ̀mí fẹ́ ṣe é, ṣugbọn ara kò lágbára.” Ó tún lọ gbadura lẹẹkeji. Ó ní, “Baba mi, bí kò bá ṣeéṣe pé kí ife kíkorò yìí fò mí ru, tí ó jẹ́ ohun tí ó níláti ṣẹlẹ̀ sí mi, ìfẹ́ tìrẹ ni ṣíṣe.” Ó tún wá, ó tún bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí wọn ń sùn, nítorí oorun ń kùn wọ́n pupọ. Ó bá fi wọ́n sílẹ̀, ó pada lọ gbadura ní ẹẹkẹta; ó tún sọ nǹkankan náà. Lẹ́yìn náà ó wá lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ tún wà níbi tí ẹ̀ ń sùn, tí ẹ̀ ń sinmi! Ẹ wò ó! Àkókò náà súnmọ́ tòsí tí a óo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́. Ẹ dìde. Ẹ jẹ́ kí á máa lọ. Ẹni tí yóo fi mí fún àwọn ọ̀tá súnmọ́ tòsí.” Bí Jesu ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni Judasi, ọ̀kan ninu àwọn mejila yọ, pẹlu ọ̀pọ̀ eniyan tí wọ́n mú idà ati kùmọ̀ lọ́wọ́. Wọ́n ń bọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ìlú. Ẹni tí ó fi í fún àwọn ọ̀tá ti fi àmì fún wọn pé, “Ẹni tí mo bá kí, tí mo fi ẹnu kàn ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ni ẹni náà. Ẹ mú un.” Lẹsẹkẹsẹ bí ó ti dé ọ̀dọ̀ Jesu, ó ní, “Ẹ pẹ̀lẹ́ o, Olùkọ́ni.” Ni ó bá da ẹnu dé e ní ẹ̀rẹ̀kẹ́. Jesu sọ fún un pé, “Ọ̀rẹ́ kí ló dé o?” Nígbà náà ni àwọn eniyan wá, wọ́n ṣùrù mọ́ Jesu, wọ́n mú un. Ọ̀kan ninu àwọn tí ó wà pẹlu Jesu bá na ọwọ́, ó fa idà yọ, ó sì fi ṣá ẹrú Olórí Alufaa kan, ó gé e létí. Ṣugbọn Jesu sọ fún un pé, “Ti idà rẹ bọ inú akọ rẹ̀ pada, nítorí gbogbo àwọn tí ó bá ń fa idà yọ, idà ni a óo fi pa wọ́n. Tabi o kò mọ̀ pé mo lè ké pe Baba mi, kí ó fún mi ní ẹgbaagbeje angẹli nisinsinyii? Ṣugbọn bí mo bá ṣe bẹ́ẹ̀ báwo ni Ìwé Mímọ́ yóo ti ṣe ṣẹ pé bẹ́ẹ̀ ni ó gbọdọ̀ rí?” Jesu bá sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ jáde wá mú mi pẹlu idà ati kùmọ̀ bí ìgbà tí ẹ wá mú olè. Ojoojumọ ni mò ń jókòó ninu Tẹmpili láti kọ́ àwọn eniyan. Ẹ kò mú mi nígbà náà! Ṣugbọn gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ kí ọ̀rọ̀ àwọn wolii lè ṣẹ ni.” Gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bá fi í sílẹ̀, wọ́n sálọ. Àwọn tí wọ́n mú Jesu fà á lọ sọ́dọ̀ Kayafa Olórí Alufaa, níbi tí àwọn amòfin ati àwọn àgbà ti pé jọ sí. Peteru ń tẹ̀lé Jesu, ó ń bọ̀ lẹ́yìn patapata, títí ó fi dé àgbàlá Olórí Alufaa. Ó wọlé, ó jókòó pẹlu àwọn ẹ̀ṣọ́ láti rí ibi tí gbogbo rẹ̀ yóo yọrí sí. Àwọn olórí alufaa ati gbogbo ìgbìmọ̀ ń wá ẹ̀rí èké tí ó lè kóbá Jesu kí wọn baà lè pa á. Ṣugbọn wọn kò rí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọpọlọpọ ni àwọn ẹlẹ́rìí-èké tí wọ́n yọjú. Ní ìgbẹ̀yìn àwọn meji kan wá. Wọ́n ní, “Ọkunrin yìí sọ pé, ‘Mo lè wó Tẹmpili Ọlọrun yìí, kí n sì tún un kọ́ ní ọjọ́ mẹta.’ ” Olórí Alufaa bá dìde, ó ní, “O kò fèsì rárá? Àbí o kò gbọ́ ohun tí wọ́n sọ pé o wí?” Ṣugbọn Jesu kò fọhùn. Olórí Alufaa wá sọ fún un pé, “Mo fi Ọlọrun alààyè bẹ̀ ọ́, sọ fún wa bí ìwọ ni Mesaya, Ọmọ Ọlọrun.” Jesu dá a lóhùn pé, “Ẹnu ara rẹ ni o fi sọ ọ́; ṣugbọn mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé láti ìsinsìnyìí lọ, ẹ óo rí Ọmọ-Eniyan tí ó jókòó lórí ìtẹ́ pẹlu agbára Ọlọrun, tí ìkùukùu yóo sì máa gbé e bọ̀ wá.” Olórí Alufaa bá fa aṣọ rẹ̀ ya, ó ní, “O sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun. Ẹlẹ́rìí wo ni a tún ń wá? Ẹ ti gbọ́ ọ̀rọ̀ àfojúdi tí ó sọ sí Ọlọrun nisinsinyii. Kí ni ẹ rò?” Wọ́n dáhùn pé, “Ikú ni ó tọ́ sí i.” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí tutọ́ sí i lójú, wọ́n ń sọ ọ́ lẹ́ṣẹ̀ẹ́, wọ́n ń gbá a létí. Wọ́n ń sọ pé, “Ìwọ, Mesaya, sọ ẹni tí ó lù ọ́ fún wa!” Peteru jókòó lóde ní àgbàlá. Ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹbinrin wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “Ìwọ náà wà pẹlu Jesu ará Galili.” Ṣugbọn Peteru sẹ́ níwájú gbogbo wọn, ó ní, “N kò mọ ohun tí ò ń sọ.” Bí ó ti ń lọ sí ẹnu ọ̀nà, iranṣẹbinrin mìíràn tún rí i, ó bá sọ fún àwọn tí ó wà níbẹ̀ pé, “Ọkunrin yìí wà pẹlu Jesu ará Nasarẹti.” Peteru tún sẹ́, ó búra pé, “N kò mọ ọkunrin náà.” Ó ṣe díẹ̀ si, àwọn tí ó dúró níbẹ̀ tọ Peteru lọ, wọ́n sọ fún un pé, “Òtítọ́ ni pé ọ̀kan ninu wọn ni ìwọ náà í ṣe nítorí ọ̀rọ̀ rẹ fihàn bẹ́ẹ̀!” Nígbà náà ni Peteru bẹ̀rẹ̀ sí ṣépè, ó tún ń búra pé, “N kò mọ ọkunrin náà.” Lẹsẹkẹsẹ àkùkọ kọ. Peteru wá ranti ọ̀rọ̀ tí Jesu sọ, pé, “Kí àkùkọ tó kọ, ìwọ yóo sẹ́ mi ní ẹẹmẹta.” Ó bá bọ́ sóde, ó sọkún gidigidi. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, gbogbo àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ìlú jọ forí-korí nípa ọ̀ràn Jesu, kí wọ́n lè pa á. Wọ́n dè é, wọ́n bá fà á lọ láti fi lé Pilatu, gomina, lọ́wọ́. Nígbà tí Judasi, ẹni tí ó fi Jesu fún àwọn ọ̀tá rí i pé a dá Jesu lẹ́bi, ó ronupiwada. Ó bá lọ dá ọgbọ̀n owó fadaka pada fún àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà. Ó ní, “Mo ṣẹ̀ ní ti pé mo ṣe ikú pa aláìṣẹ̀.” Wọ́n bá dá a lóhùn pé, “Èwo ló kàn wá ninu rẹ̀? Ẹjọ́ tìrẹ ni.” Judasi bá da owó náà sílẹ̀ ninu Tẹmpili, ó jáde, ó bá lọ pokùnso. Àwọn olórí alufaa mú owó fadaka náà, wọ́n ní, “Kò tọ́ fún wa láti fi í sinu àpò ìṣúra Tẹmpili mọ́ nítorí owó ẹ̀jẹ̀ ni.” Lẹ́yìn tí wọ́n ti forí-korí, wọ́n fi owó náà ra ilẹ̀ amọ̀kòkò fún ìsìnkú àwọn àlejò. Ìdí nìyí ti a fi ń pe ilẹ̀ náà ní, “Ilẹ̀ ẹ̀jẹ̀” títí di òní olónìí. Báyìí ni ohun tí wolii Jeremaya, wí ṣẹ, nígbà tí ó sọ pé, “Wọ́n mú ọgbọ̀n owó fadaka náà, iye tí a dá lé orí ẹ̀mí náà, nítorí iye tí àwọn ọmọ Israẹli ń dá lé eniyan lórí nìyí, wọ́n lo owó náà fún ilẹ̀ amọ̀kòkò, gẹ́gẹ́ bí Oluwa ti pàṣẹ fún mi.” Jesu bá dúró siwaju gomina. Gomina bi í pé, “Ìwọ ni ọba àwọn Juu bí?” Jesu ní, “O ti fi ẹnu ara rẹ sọ ọ́.” Ṣugbọn bí àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ti ń fi ẹ̀sùn kàn án tó, kò fèsì rárá. Nígbà náà ni Pilatu sọ fún un pé, “O kò gbọ́ irú ẹ̀sùn tí wọn ń fi kàn ọ́ ni?” Ṣugbọn Jesu kò dá a lóhùn gbolohun kan ṣoṣo, tí ó fi jẹ́ pé ẹnu ya gomina pupọ. Gẹ́gẹ́ bí àṣà, ní àkókò àjọ̀dún, gomina a máa dá ẹlẹ́wọ̀n kan sílẹ̀ fún àwọn eniyan, ẹnikẹ́ni tí wọn bá fẹ́. Ní àkókó náà, ẹlẹ́wọ̀n olókìkí kan wà tí ó ń jẹ́ Jesu Baraba. Nígbà tí àwọn Juu pésẹ̀, Pilatu bi wọ́n pé, “Ta ni kí n dá sílẹ̀ fun yín, Jesu Baraba ni tabi Jesu tí ó ń jẹ́ Mesaya?” Pilatu ti mọ̀ pé nítorí ìlara ni wọ́n fi mú un wá sọ́dọ̀ òun. Nígbà tí Pilatu jókòó lórí pèpéle ìdájọ́, iyawo rẹ̀ ranṣẹ sí i, ó ní, “Má ṣe lọ́wọ́ ninu ọ̀ràn ọkunrin olódodo yìí. Nítorí pé mọ́jú òní, ojú mi rí nǹkan lójú àlá nípa rẹ̀.” Àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ti rọ àwọn eniyan láti bèèrè fún Baraba, kí wọ́n pa Jesu. Gomina bi wọ́n pé, “Ta ni ninu àwọn meji yìí ni ẹ fẹ́ kí n dá sílẹ̀ fun yín?” Wọ́n sọ pé, “Baraba ni.” Pilatu wá bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ fẹ́ kí n ṣe sí Jesu tí ó ń jẹ́ Mesaya?” Gbogbo wọn dáhùn pé, “Kàn án mọ́ agbelebu.” Pilatu bi wọ́n pé, “Ohun burúkú wo ni ó ṣe?” Ṣugbọn wọ́n túbọ̀ kígbe pé, “Kàn án mọ́ agbelebu.” Nígbà tí Pilatu rí i pé òun kò lè yí wọn lọ́kàn pada, ati pé rògbòdìyàn fẹ́ bẹ́ sílẹ̀, ó mú omi, ó fọ ọwọ́ rẹ̀ níwájú wọn. Ó ní, “N kò lọ́wọ́ ninu ikú ọkunrin yìí. Ẹ̀yin ni kí ẹ mójútó ọ̀ràn náà.” Gbogbo àwọn eniyan náà dáhùn pé, “Kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà lórí àwa ati àwọn ọmọ wa!” Pilatu bá dá Baraba sílẹ̀ fún wọn. Lẹ́yìn tí ó ti pàṣẹ pé kí wọ́n na Jesu ní pàṣán, ó fi í lé wọn lọ́wọ́ láti kàn mọ̀ agbelebu. Àwọn ọmọ-ogun gomina bá mú Jesu lọ sí ibùdó wọn, gbogbo wọn bá péjọ lé e lórí. Wọ́n bọ́ ẹ̀wù rẹ̀, wọ́n wá fi aṣọ àlàárì bò ó lára. Wọ́n fi ẹ̀gún hun adé, wọ́n fi dé e lórí. Wọ́n fi ọ̀pá sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀. Wọ́n wá ń kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́; wọ́n ń wí pé, “Kabiyesi, ọba àwọn Juu.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń tutọ́ sí i lára. Wọ́n mú ọ̀pá, wọ́n ń kán an mọ́ ọn lórí. Nígbà tí wọn ti fi ṣe ẹlẹ́yà tẹ́rùn, wọ́n bọ́ aṣọ àlàárì náà kúrò lára rẹ̀, wọ́n fi tirẹ̀ wọ̀ ọ́. Wọ́n bá mú un lọ láti kàn án mọ́ agbelebu. Nígbà tí wọn ń jáde lọ, wọ́n rí ọkunrin kan ará Kirene tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Simoni. Wọ́n bá fi ipá mú un láti ru agbelebu Jesu. Nígbà tí wọ́n dé ibi tí wọn ń pè ní Gọlgọta (ìtumọ̀ èyí tíí ṣe “Ibi Agbárí”), wọ́n fún un ní ọtí kíkorò mu. Nígbà tí ó tọ́ ọ wò, ó kọ̀, kò mu ún. Nígbà tí wọ́n kàn án mọ́ agbelebu tán, wọ́n pín aṣọ rẹ̀ mọ́ ara wọn lọ́wọ́, wọ́n ṣẹ́ gègé láti mọ èyí tí yóo kan ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn. Wọ́n bá jókòó níbẹ̀, wọ́n ń ṣọ́ ọ. Wọ́n fi àkọlé kan kọ́ sí òkè orí rẹ̀, wọ́n kọ ẹ̀sùn tí a fi kàn án sibẹ pé, “Eléyìí ni Jesu ọba àwọn Juu.” Wọ́n tún kan àwọn ọlọ́ṣà meji mọ́ agbelebu pẹlu rẹ̀, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, ekeji ní ọwọ́ òsì rẹ̀. Àwọn tí ó ń kọjá lọ ń sọ ìsọkúsọ sí i. Wọ́n ń já apá mọ́nú, wọ́n ń sọ pé, “Ìwọ tí yóo wó Tẹmpili, tí yóo tún un kọ́ ní ọjọ́ mẹta, gba ara rẹ là. Bí Ọmọ Ọlọrun bá ni ọ́, sọ̀kalẹ̀ kúrò lórí agbelebu.” Bákan náà ni àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin ati àwọn àgbà, àwọn náà ń fi í ṣe ẹlẹ́yà. Wọ́n ń sọ pé, “Àwọn ẹlòmíràn ni ó rí gbà là, kò lè gba ara rẹ̀ là. Ṣé ọba Israẹli ni! Kí ó sọ̀kalẹ̀ nisinsinyii láti orí agbelebu, a óo gbà á gbọ́. Ṣé ó gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun ni! Kí Ọlọrun gbà á sílẹ̀ nisinsinyii bí ó bá fẹ́ ẹ! Ṣebí ó sọ pé ọmọ Ọlọrun ni òun.” Bákan náà ni àwọn ọlọ́ṣà tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu pẹlu rẹ̀ fi ń ṣe ẹlẹ́yà. Láti agogo mejila ọ̀sán ni òkùnkùn ti bo gbogbo ilẹ̀ títí di agogo mẹta ọ̀sán. Nígbà tí ó tó nǹkan bí agogo mẹta ọ̀sán, Jesu kígbe ní ohùn rara pé, “Eli, Eli, lema sabakitani?” Ìtumọ̀ èyí ni, “Ọlọrun mi! Ọlọrun mi! Kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀?” Nígbà tí àwọn kan tí ó dúró níbẹ̀ gbọ́, wọ́n ní, “Ọkunrin yìí ń pe Elija.” Lẹsẹkẹsẹ ọ̀kan ninu wọn sáré, ó ti nǹkankan bíi kànìnkànìn bọ inú ọtí kíkan, ó fi sórí ọ̀pá láti fi fún un mu. Ṣugbọn àwọn yòókù ń sọ pé, “Fi í sílẹ̀! Jẹ́ kí a wò bí Elija yóo wá gbà á là.” Jesu bá tún kígbe tòò, ó mí kanlẹ̀, ó bá dákẹ́. Aṣọ ìkélé tí ó wà ninu Tẹmpili ya sí meji láti òkè dé ilẹ̀. Ilẹ̀ mì tìtì. Àwọn òkè sán. Òkúta ẹnu ibojì ṣí, a sì jí ọ̀pọ̀ òkú àwọn olódodo dìde. Wọ́n jáde kúrò ninu ibojì lẹ́yìn tí Jesu ti jí dìde, wọ́n wọ Jerusalẹmu lọ, ọpọlọpọ eniyan ni ó rí wọn. Nígbà tí ọ̀gágun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ tí wọn ń ṣọ́ Jesu rí ilẹ̀ tí ó mì ati gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ẹ̀rù bà wọ́n pupọ. Wọ́n ní, “Nítòótọ́ Ọmọ Ọlọrun ni ọkunrin yìí.” Ọ̀pọ̀ àwọn obinrin wà níbẹ̀ tí wọ́n dúró ní òkèèrè réré, tí wọn ń wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Àwọn ni wọ́n tí ń tẹ̀lé Jesu láti Galili, tí wọn ń ṣe iranṣẹ fún un. Maria Magidaleni wà lára wọn, ati Maria ìyá Jakọbu ati ti Josẹfu ati ìyá àwọn ọmọ Sebede. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan, ará Arimatia tí ó ń jẹ́ Josẹfu wá. Òun náà jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu. Ó tọ Pilatu lọ láti bèèrè òkú Jesu. Pilatu bá pàṣẹ pé kí wọ́n fún un. Nígbà tí Josẹfu ti gba òkú náà, ó fi aṣọ funfun tí ó mọ́ wé e. Ó tẹ́ ẹ sí inú ibojì rẹ̀ titun tí òun tìkalárarẹ̀ ti gbẹ́ sí inú àpáta. Ó yí òkúta ńlá kan dí ẹnu ọ̀nà ibojì náà. Ó bá kúrò níbẹ̀. Maria Magidaleni ati Maria keji wà níbẹ̀, wọ́n jókòó ní iwájú ibojì náà. Ní ọjọ́ keji, ọjọ́ tí ó tẹ̀lé ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ àjọ̀dún, àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi wá sọ́dọ̀ Pilatu. Wọ́n ní, “Alàgbà, a ranti pé ẹlẹ́tàn nì sọ nígbà tí ó wà láàyè pé lẹ́yìn ọjọ́ mẹta òun óo jí dìde. Nítorí náà, pàṣẹ kí wọ́n ṣọ́ ibojì náà títí di ọjọ́ kẹta. Bí a kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lè wá jí òkú rẹ̀ lọ, wọn yóo wá wí fún àwọn eniyan pé, ‘Ó ti jinde kúrò ninu òkú.’ Ìtànjẹ ẹẹkeji yóo wá burú ju ti àkọ́kọ́ lọ.” Pilatu bá dá wọn lóhùn pé, “Ṣebí ẹ ní olùṣọ́. Ẹ lọ fi wọ́n ṣọ́ ibojì náà bí ó ti tọ́ lójú yín.” Wọ́n bá lọ, wọ́n sé ẹnu ibojì náà, wọ́n fi èdìdì sí ara òkúta tí wọ́n gbé dí i. Wọ́n sì fi àwọn olùṣọ́ sibẹ pẹlu. Nígbà tí Ọjọ́ Ìsinmi ti kọjá, tí ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, Maria Magidaleni ati Maria keji wá wo ibojì Jesu. Ilẹ̀ mì tìtì, nítorí angẹli Oluwa sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá. Ó yí òkúta tí ó wà lẹ́nu ibojì kúrò, ó sì jókòó lórí rẹ̀. Ìrísí rẹ̀ dàbí mànàmáná. Aṣọ rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Ẹ̀rù mú kí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ibojì náà gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, kí wọn sì kú sára. Angẹli náà sọ fún àwọn obinrin náà pé, “Ẹ má bẹ̀rù. Mo mọ̀ pé Jesu tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu ni ẹ̀ ń wá. Kò sí níhìn-ín, nítorí ó ti jí dìde, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ. Ẹ wá wo ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí. Ẹ lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wéré, pé ó ti jí dìde kúrò ninu òkú. Ó ti ṣáájú yín lọ sí Galili; níbẹ̀ ni ẹ óo ti rí i. Ohun tí mo ní sọ fun yín nìyí.” Àwọn obinrin náà bá yára kúrò níbi ibojì náà pẹlu ìbẹ̀rùbojo ati ayọ̀ ńlá, wọ́n sáré lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Lójijì Jesu pàdé wọn, ó kí wọn, ó ní, “Ẹ pẹ̀lẹ́ o!” Wọ́n bá dì mọ́ ọn lẹ́sẹ̀, wọ́n júbà rẹ̀. Jesu wá sọ fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù. Ẹ lọ sọ fún àwọn arakunrin mi pé kí wọ́n lọ sí Galili; níbẹ̀ ni wọn yóo ti rí mi.” Bí wọ́n ti ń lọ, àwọn kan ninu àwọn tí wọ́n fi ṣọ́ ibojì lọ sí inú ìlú láti sọ ohun gbogbo tí ó ṣẹlẹ̀ fún àwọn olórí alufaa. Nígbà tí àwọn olórí alufaa ti forí-korí pẹlu àwọn àgbà, wọ́n wá owó tí ó jọjú fún àwọn ọmọ-ogun náà. Wọ́n sì kọ́ wọn pé, “Ẹ sọ pé, ‘Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá lóru láti jí òkú rẹ̀ nígbà tí a sùn lọ.’ Bí ìròyìn yìí bá dé etí gomina, a óo bá a sọ̀rọ̀, kò ní sí ohunkohun tí yóo ṣẹ̀rù bà yín.” Àwọn ọmọ-ogun náà bá gba owó tí wọ́n fún wọn, wọ́n ṣe bí wọ́n ti kọ́ wọn. Èyí náà sì ni ìtàn tí àwọn Juu ń sọ káàkiri títí di òní olónìí. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọkanla lọ sí Galili, sí orí òkè tí Jesu ti sọ fún wọn. Nígbà tí wọn rí i, wọ́n júbà rẹ̀, ṣugbọn àwọn kan ninu wọn ń ṣiyèméjì. Jesu wá sọ́dọ̀ wọn, ó sọ fún wọn pé, “A ti fún mi ní gbogbo àṣẹ ní ọ̀run ati ní ayé. Nítorí náà kí ẹ lọ sọ gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ-ẹ̀yìn mi; kí ẹ máa ṣe ìrìbọmi fún wọn ní orúkọ Baba ati ti Ọmọ ati ti Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ máa kọ́ wọn láti kíyèsí gbogbo nǹkan tí mo pa láṣẹ fun yín. Kí ẹ mọ̀ dájú pé mo wà pẹlu yín ní ìgbà gbogbo, títí dé òpin ayé.” Bí ìyìn rere Jesu Kristi Ọmọ Ọlọrun ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyí: Gẹ́gẹ́ bí wolii Aisaya ti kọ ọ́ tẹ́lẹ̀ ni ó rí: “Ọlọrun ní, ‘Wò ó! Mo rán oníṣẹ́ mi ṣiwaju rẹ òun ni yóo palẹ̀ mọ́ dè ọ́.’ Ohùn ẹni tí ń kígbe ninu aṣálẹ̀ pé, ‘Ẹ la ọ̀nà tí Oluwa yóo gbà, ẹ ṣe é kí ó tọ́ fún un láti rìn.’ ” Báyìí ni Johanu bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìrìbọmi ninu aṣálẹ̀, tí ó ń waasu pé kí àwọn eniyan ronupiwada, kí wọ́n ṣe ìrìbọmi, kí Ọlọrun lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wọ́n. Gbogbo eniyan ilẹ̀ Judia ati ti ìlú Jerusalẹmu jáde tọ̀ ọ́ lọ, wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ó sì ń ṣe ìrìbọmi fún wọn ninu odò Jọdani. Irun ràkúnmí ni wọ́n fi hun aṣọ tí Johanu wọ̀, ọ̀já ìgbànú aláwọ ni ó gbà mọ́ ìdí, eṣú ni ó ń jẹ, ó sì ń lá oyin ìgàn. Ó ń waasu pé, “Ẹnìkan tí ó jù mí lọ ń bọ̀ lẹ́yìn mi, n kò tó bẹ̀rẹ̀ láti tú okùn bàtà rẹ̀. Ìrìbọmi ni èmi ń ṣe fun yín ṣugbọn òun yóo fi Ẹ̀mí Mímọ́ wẹ̀ yín mọ́.” Ní ọjọ́ kan, Jesu wá láti Nasarẹti ìlú kan ní Galili, Johanu bá ṣe ìrìbọmi fún un ninu odò Jọdani. Bí Jesu ti ń jáde kúrò ninu omi, lẹ́sẹ̀ kan náà ó rí Ẹ̀mí Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí àdàbà tí ó bà lé e. Ó sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run tí ó wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ ọmọ mi, inú mi dùn sí ọ gidigidi.” Lẹ́yìn èyí, Ẹ̀mí Ọlọrun gbé Jesu lọ sinu aṣálẹ̀. Ó wà níbẹ̀ fún ogoji ọjọ́ tí Satani ń dán an wò. Ààrin àwọn ẹranko ni ó wà, ṣugbọn àwọn angẹli ń ṣe iranṣẹ fún un. Lẹ́yìn ìgbà tí wọn ju Johanu sinu ẹ̀wọ̀n, Jesu wá sí Galili, ó ń waasu ìyìn rere tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá. Ó ń wí pé, “Àkókò tó; ìjọba Ọlọrun súnmọ́ ìtòsí. Ẹ ronupiwada, kí ẹ gba ìyìn rere gbọ́.” Bí Jesu ti ń rìn lọ lẹ́bàá òkun Galili, ó rí Simoni ati Anderu arakunrin rẹ̀ tí wọn ń da àwọ̀n sinu òkun, nítorí apẹja ni wọ́n. Jesu bá wí fún wọn pé, “Ẹ wá máa tẹ̀lé mi, èmi yóo sọ yín di ẹni tí ó ń fa eniyan bí a ti ń dẹ ẹja ninu omi.” Lẹ́sẹ̀ kan náà wọ́n bá fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n ń tẹ̀lé e. Bí ó ti rìn siwaju díẹ̀ sí i, ó rí Jakọbu ọmọ Sebede ati Johanu arakunrin rẹ̀ ninu ọkọ̀, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe. Bí Jesu ti rí wọn, ó pè wọ́n. Wọ́n bá fi Sebede baba wọn sílẹ̀ ninu ọkọ̀ pẹlu àwọn alágbàṣe, wọ́n ń tẹ̀lé e. Wọ́n lọ sí Kapanaumu. Ní Ọjọ́ Ìsinmi àwọn Juu, Jesu lọ sí ilé ìpàdé, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn eniyan. Ẹnu ya àwọn tí ó gbọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀, nítorí ó ń kọ́ wọn bí ẹni tí ó ní àṣẹ, yàtọ̀ sí bí àwọn amòfin ṣe ń kọ́ wọn. Ọkunrin kan wà ninu ilé ìpàdé náà tí ó ní ẹ̀mí èṣù. Ó bá kígbe tòò, ó ní, “Kí ni ó pa tàwa-tìrẹ pọ̀, Jesu ará Nasarẹti? Ṣé o dé láti pa wá run ni? Mo mọ ẹni tí o jẹ́. Ẹni Mímọ́ Ọlọrun ni ọ́.” Jesu bá bá a wí, ó ní, “Pa ẹnu mọ́, kí o jáde kúrò ninu ọkunrin yìí.” Ẹ̀mí èṣù náà bá gbo ọkunrin náà jìgìjìgì, ó kígbe tòò, ó sì jáde kúrò ninu ọkunrin náà. Kẹ́kẹ́ bá pamọ́ gbogbo àwọn eniyan lẹ́nu tóbẹ́ẹ̀ tí wọn ń wí láàrin ara wọn pé, “Kí ni èyí? Ẹ̀kọ́ titun ni! Pẹlu àṣẹ ni ó fi bá àwọn ẹ̀mí èṣù wí, wọ́n sì gbọ́ràn sí i lẹ́nu.” Òkìkí Jesu wá kan ká gbogbo ìgbèríko Galili. Bí wọ́n ti jáde kúrò ninu ilé ìpàdé, Jesu pẹlu Jakọbu ati Johanu lọ sí ilé Simoni ati Anderu. Ìyá iyawo Simoni wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn ibà. Lẹsẹkẹsẹ wọ́n sọ fún Jesu nípa rẹ̀. Ó bá lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó fà á lọ́wọ́ dìde. Ibà náà sì fi í sílẹ̀, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí tọ́jú oúnjẹ fún wọn. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, tí oòrùn wọ̀, àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí gbé gbogbo àwọn tí ara wọn kò dá ati àwọn tí wọ́n ní ẹ̀mí èṣù wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Gbogbo ìlú péjọ sí ẹnu ọ̀nà. Ó ṣe ìwòsàn fún ọpọlọpọ àwọn tí ó ní oríṣìíríṣìí àìsàn, ó tún lé ẹ̀mí èṣù jáde. Kò jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí èṣù náà sọ̀rọ̀, nítorí wọ́n mọ ẹni tí ó jẹ́. Ní òwúrọ̀ kutukutu kí ilẹ̀ tó mọ́, Jesu dìde, ó jáde kúrò ní ilé, ó lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú láti gbadura níbi tí kò sí ẹnìkankan. Simoni ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ bá ń wá a kiri. Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n wí fún un pé, “Gbogbo eniyan ní ń wá ọ.” Ṣugbọn ó wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí àwọn abúlé mìíràn tí ó wà ní ìtòsí kí n lè waasu níbẹ̀, nítorí ohun tí mo wá sí ayé fún ni èyí.” Ó bá lọ, ó ń waasu ninu àwọn ilé ìpàdé wọn ní gbogbo ilẹ̀ Galili, ó ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ẹnìkan tí ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ń bẹ̀ ẹ́ pé, “Bí o bá fẹ́, o lè sọ ara mi di mímọ́.” Àánú ṣe Jesu ó bá na ọwọ́ ó fi kàn án, ó ní, “Mo fẹ́. Di mímọ́.” Lẹsẹkẹsẹ àrùn ẹ̀tẹ̀ náà bá kúrò lára rẹ̀, ara rẹ̀ sì dá. Jesu fi ohùn líle kìlọ̀ fún un, lẹsẹkẹsẹ ó bá ní kí ó máa lọ. Ó wí fún un pé, “Má wí ohunkohun fún ẹnikẹ́ni. Ṣugbọn lọ fi ara rẹ han alufaa, kí o sì rúbọ ìwòsàn rẹ bí Mose ti pàṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí fún wọn pé ara rẹ ti dá.” Ṣugbọn ọkunrin náà jáde lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún ọpọlọpọ eniyan, ó ń rán ọ̀rọ̀ náà mọ́ ẹnu, tóbẹ́ẹ̀ tí Jesu kò fi lè wọ inú ìlú ní gbangba mọ́, ṣugbọn ó lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú níbi tí kò sí eniyan. Sibẹ àwọn eniyan ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti ibi gbogbo. Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, Jesu tún lọ sí Kapanaumu, àwọn eniyan gbọ́ pé ó wà ninu ilé kan. Ọ̀pọ̀ eniyan bá wá péjọ sibẹ, wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi jẹ́ pé ati inú ilé, ati ẹnu ọ̀nà ni ó kún. Ó bá ń sọ̀rọ̀ ìyìn rere fún wọn. Àwọn mẹrin kan ń gbé arọ kan bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Nígbà tí wọn kò lè gbé e dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ nítorí ọ̀pọ̀ eniyan, wọ́n dá òrùlé lu ní ọ̀kánkán ibi tí Jesu wà. Nígbà tí wọ́n ti dá a lu tán, wọ́n sọ ọkunrin arọ náà kalẹ̀ ti òun ti ibùsùn rẹ̀. Nígbà tí Jesu rí igbagbọ wọn, ó wí fún arọ náà pé, “Ọmọ, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.” Ṣugbọn àwọn amòfin kan jókòó níbẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kùn sinu pé, “Kí ló dé tí eléyìí fi ń sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀? Ó ń sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun. Ta ni lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni bíkòṣe Ọlọrun nìkan?” Ṣugbọn Jesu mọ̀ ninu ara rẹ̀ pé wọ́n ń ro èrò báyìí ninu ọkàn wọn. Ó wí fún wọn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń kùn sinu? Èwo ni ó rọrùn jù: Láti wí fún arọ náà pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,’ tabi láti wí pé, ‘Dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o máa rìn?’ Ṣugbọn kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ-Eniyan ní àṣẹ ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni,” ó bá wí fún arọ náà pé, “Mo wí fún ọ, dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o máa lọ sí ilé rẹ.” Ọkunrin náà bá dìde lẹsẹkẹsẹ, ó gbé ibùsùn rẹ̀, ó bá jáde lọ lójú gbogbo wọn. Ẹnu ya gbogbo wọn, wọ́n sì ń yin Ọlọrun, wọ́n ní, “A kò rí èyí rí.” Jesu tún jáde lọ sí ẹ̀bá òkun, gbogbo àwọn eniyan ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó bá ń kọ́ wọn. Bí ó ti ń lọ, ó rí Lefi ọmọ Alfeu tí ó jókòó níbi tí ó ti ń gba owó-odè. Ó wí fún un pé, “Máa tẹ̀lé mi.” Lefi bá dìde, ó sì tẹ̀lé e. Bí Jesu ti jókòó ní ilé Lefi, ọpọlọpọ àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń bá Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jẹun, nítorí wọ́n pọ̀ tí wọn ń tẹ̀lé e. Nígbà tí àwọn amòfin ninu àwọn Farisi rí i tí ó ń bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ati àwọn agbowó-odè jẹun, wọ́n bi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ léèrè pé, “Kí ló dé tí ó fi ń bá àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun?” Nígbà tí Jesu gbọ́, ó wí fún wọn pé, “Àwọn tí ara wọn le kò nílò oníṣègùn bíkòṣe àwọn tí ara wọn kò dá: èmi kò wá láti pe àwọn olódodo bíkòṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ati àwọn Farisi ń gbààwẹ̀ ní àkókò kan. Àwọn kan wá, wọ́n ń bi Jesu pé, “Kí ló dé tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn Farisi a máa gbààwẹ̀ ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tìrẹ kì í gbààwẹ̀?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ iyawo kò lè máa gbààwẹ̀ nígbà tí ọkọ iyawo wà lọ́dọ̀ wọn, níwọ̀n ìgbà tí ọkọ iyawo bá wà pẹlu wọn, wọ́n kò lè máa gbààwẹ̀. Ṣugbọn ọjọ́ ń bọ̀, tí a óo gba ọkọ iyawo kúrò lọ́dọ̀ wọn, wọn óo gbààwẹ̀ nígbà náà. “Kò sí ẹni tíí fi ìrépé asọ titun tí kò ì tíì wọ omi rí lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù. Tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, aṣọ titun náà yóo súnkì lára ẹ̀wù náà, yóo wá tún fà á ya ju ti àkọ́kọ́ lọ. Kò sí ẹni tíí fi ọtí titun sinu ògbólógbòó àpò awọ. Tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọtí náà yóo bẹ́ àpò náà, ati ọtí ati àpò yóo bá ṣòfò. Ṣugbọn inú àpò awọ titun ni à ń fi ọtí titun sí.” Ní àkókò kan ní Ọjọ́ Ìsinmi, bí Jesu ti ń la ààrin oko ọkà kọjá, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí já ọkà jẹ bí wọn tí ń lọ lọ́nà. Àwọn Farisi wí fún un pé, “Wò bí wọn ti ń ṣe ohun tí kò tọ́ láti ṣe ní Ọjọ́ Ìsinmi!” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ kò ì tíì ka ohun tí Dafidi ṣe, nígbà tí kò ní oúnjẹ, tí ebi ń pa òun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀? Bí ó ti wọ ilé Ọlọrun lọ ní àkókò Abiatari Olórí Alufaa, tí ó jẹ burẹdi tí ó wà lórí tabili níwájú Oluwa, tí kò yẹ kí ẹnikẹ́ni jẹ, àfi alufaa nìkan, tí ó tún fún àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ jẹ?” Ó wá wí fún wọn pé, “Lílò eniyan ni a dá Ọjọ́ Ìsinmi fún, a kò dá eniyan fún Ọjọ́ Ìsinmi. Nítorí náà, Ọmọ-Eniyan ni Oluwa ohun gbogbo ati ti Ọjọ́ Ìsinmi pẹlu.” Jesu tún wọ inú ilé ìpàdé lọ. Ọkunrin kan wà níbẹ̀ tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ. Àwọn kan wà tí wọn ń ṣọ́ ọ bí yóo wo ọkunrin yìí sàn ní Ọjọ́ Ìsinmi, kí wọn lè fi í sùn. Ó wí fún ọkunrin náà tí ọwọ́ rẹ̀ rọ pé, “Dìde dúró ní ààrin àwùjọ.” Jesu bá bi wọ́n léèrè pé, “Èwo ni ó dára: láti ṣe ìrànlọ́wọ́ ni tabi láti ṣe ìbàjẹ́ ní Ọjọ́ Ìsinmi? Láti gba ẹ̀mí là ni tabi láti pa ẹ̀mí run?” Ṣugbọn wọn kò fọhùn. Jesu wò yíká pẹlu ibinu, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí pé ọkàn wọn le. Ó wá wí fún ọkunrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ.” Ó bá nà án. Ọwọ́ rẹ̀ sì bọ́ sípò. Lẹsẹkẹsẹ àwọn Farisi jáde lọ láti gbìmọ̀ pọ̀ pẹlu àwọn alátìlẹ́yìn Hẹrọdu lórí ọ̀nà tí wọn yóo gbà pa á. Jesu pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ yẹra lọ sí ẹ̀bá òkun. Ogunlọ́gọ̀ eniyan sì ń tẹ̀lé e. Wọ́n wá láti Galili ati Judia ati Jerusalẹmu; láti Idumea ati apá ìlà oòrùn odò Jọdani ati agbègbè Tire ati ti Sidoni. Ogunlọ́gọ̀ eniyan wọ́ lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tí ó ń ṣe. Ó bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọn tọ́jú ọkọ̀ ojú omi kan sí ìtòsí nítorí àwọn eniyan, kí wọn má baà fún un pa. Nítorí ó wo ọpọlọpọ sàn tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn aláìsàn ń ti ara wọn, kí wọ́n lè fi ọwọ́ kàn án. Nígbà tí àwọn ẹ̀mí èṣù bá rí i, wọ́n a wolẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n a máa kígbe pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọrun.” Kíkìlọ̀ ni ó máa ń kìlọ̀ fún wọn gan-an kí wọn má ṣe fi òun hàn. Lẹ́yìn náà, ó wá gun orí òkè lọ, ó pe àwọn tí ó wù ú sọ́dọ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lọ. Ó bá yan àwọn mejila, ó pè wọ́n ní aposteli, kí wọn lè wà pẹlu rẹ̀, kí ó lè máa rán wọn lọ waasu, kí wọn lè ní àṣẹ láti máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Àwọn mejila tí ó yàn náà nìyí: Simoni, tí ó sọ ní Peteru, ati Jakọbu ọmọ Sebede ati Johanu àbúrò rẹ̀, ó sọ wọ́n ní Boanage, ìtumọ̀ èyí tíí ṣe “Àwọn ọmọ ààrá”; ati Anderu, Filipi, Batolomiu, Matiu, ati Tomasi, Jakọbu ọmọ Alfeu, Tadiu, ati Simoni, ọmọ ẹgbẹ́ ìbílẹ̀ Kenaani, ati Judasi Iskariotu ẹni tí ó fi Jesu fún àwọn ọ̀tá rẹ̀. Lẹ́yìn náà, Jesu wọ inú ilé lọ, àwọn eniyan tún pé jọ tóbẹ́ẹ̀ tí òun ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kò fi lè jẹun. Nígbà tí àwọn ẹbí rẹ̀ gbọ́, wọ́n jáde lọ láti fi agbára mú un nítorí àwọn eniyan ń wí pé, “Orí rẹ̀ ti dàrú.” Ṣugbọn àwọn amòfin tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá láti Jerusalẹmu sọ pé, “Ó ní ẹ̀mí Beelisebulu; ati pé nípa agbára olórí àwọn ẹ̀mí èṣù ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.” Jesu wá pè wọ́n sọ́dọ̀, ó fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Báwo ni Satani ti ṣe lè lé Satani jáde? Bí ìjọba kan náà bá gbé ogun ti ara rẹ̀, ìjọba náà yóo parun. Bí àwọn ará ilé kan náà bá ń bá ara wọn jà, ilé náà kò lè fi ìdí múlẹ̀. Bí Satani bá gbógun ti ara rẹ̀, tí ó ń bá ara rẹ̀ jà, kò lè fi ẹsẹ̀ múlẹ̀, a jẹ́ pé ó parí fún un. “Ṣugbọn kò sí ẹnìkan tí ó lè wọ ilé alágbára kan lọ, kí ó kó dúkìá rẹ̀ láìjẹ́ pé ó kọ́ de alágbára náà mọ́lẹ̀, nígbà náà ni yóo tó lè kó ilé rẹ̀. “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ni a óo dárí ji àwọn ọmọ eniyan, ati gbogbo ìsọkúsọ tí wọ́n lè máa sọ. Ṣugbọn ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ẹ̀mí Mímọ́ kò lè ní ìdáríjì laelae, ṣugbọn ó jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ títí lae.” (Jesu sọ èyí nítorí wọ́n ń wí pé ó ní ẹ̀mí Èṣù.) Nígbà tí ó yá ìyá rẹ̀ ati àwọn arakunrin rẹ̀ wá, wọ́n dúró lóde, wọ́n bá ranṣẹ pè é. Àwọn eniyan jókòó yí i ká, wọ́n bá sọ fún un pé, “Gbọ́ ná, ìyá rẹ ati àwọn arakunrin rẹ ń bèèrè rẹ lóde.” Ó dá wọn lóhùn pé, “Ta ni ìyá mi ati arakunrin mi?” Nígbà tí ó wo gbogbo àwọn tí ó jókòó yí i ká lọ́tùn-ún lósì, ó ní, “Ẹ̀yin ni ìyá mi ati arakunrin mi. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe ohun tí ó wu Ọlọrun, òun ni arakunrin mi, ati arabinrin mi, ati ìyá mi.” Jesu tún bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn eniyan lẹ́bàá òkun. Ogunlọ́gọ̀ eniyan péjọ pọ̀ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi níláti bọ́ sin ọkọ̀ ojú omi kan, ó bá jókòó níbẹ̀ lójú omi. Gbogbo àwọn eniyan wà ní èbúté, wọ́n jókòó lórí iyanrìn. Ó bá ń fi òwe kọ́ wọn ní ọpọlọpọ nǹkan. Ó wí fún wọn ninu ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé: “Ẹ fi etí sílẹ̀! Ọkunrin kan jáde lọ láti fúnrúgbìn. Bí ó ti ń fúnrúgbìn lọ, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ bá wá, wọ́n ṣà á jẹ. Irúgbìn mìíràn bọ́ sí orí òkúta tí erùpẹ̀ díẹ̀ bò lórí. Láìpẹ́, wọ́n yọ sókè nítorí erùpẹ̀ ibẹ̀ kò jinlẹ̀. Nígbà tí oòrùn mú, ó jó wọn pa, nítorí wọn kò ní gbòǹgbò tí ó jinlẹ̀; wọ́n bá kú. Irúgbìn mìíràn bọ́ sí orí ilẹ̀ ẹlẹ́gùn-ún. Nígbà tí ẹ̀gún dàgbà, ó fún wọn pa, nítorí náà wọn kò so èso. Irúgbìn mìíràn bọ́ sí ilẹ̀ tí ó dára, wọ́n yọ sókè, wọ́n ń dàgbà, wọ́n sì ń so èso, òmíràn ọgbọ̀n, òmíràn ọgọta, òmíràn ọgọrun-un.” Lẹ́yìn náà Jesu ní, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́!” Nígbà tí ó ku òun nìkan, àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila bèèrè ìtumọ̀ àwọn òwe tí ó fi ń sọ̀rọ̀. Ó bá sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni a fi fún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba Ọlọrun, ṣugbọn bí òwe bí òwe ni fún àwọn ẹlòmíràn tí ó wà lóde. Kí wọn baà lè la ojú sílẹ̀ ṣugbọn kí wọn má ríran; kí wọn gbọ́ títí ṣugbọn kí òye má yé wọn; kí wọn má baà ronupiwada, kí á má baà dáríjì wọ́n.” Ó wá wí fún wọn pé, “Nígbà tí òwe yìí kò ye yín, báwo ni ẹ óo ti ṣe mọ gbogbo àwọn òwe ìyókù? Afunrugbin fúnrúgbìn ọ̀rọ̀ ìròyìn ayọ̀. Àwọn wọnyi ni ti ẹ̀bá ọ̀nà, níbi tí a fúnrúgbìn ọ̀rọ̀ náà sí: àwọn tí ó jẹ́ pé, lẹsẹkẹsẹ tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, Satani wá, ó mú ọ̀rọ̀ tí a ti fún sinu ọkàn wọn lọ. Bákan náà ni àwọn ẹlòmíràn dàbí irúgbìn tí a fún sórí òkúta, nígbà tí wọn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, wọn á fi inú dídùn gbà á. Ṣugbọn nítorí tí wọn kò ní gbòǹgbò ninu ara wọn, àkókò díẹ̀ ni ọ̀rọ̀ náà gbé ninu wọn. Nígbà tí ìyọnu tabi inúnibíni bá dé nítorí ọ̀rọ̀ náà lẹsẹkẹsẹ wọn á kùnà. Àwọn mìíràn dàbí irúgbìn tí a fún sórí ilẹ̀ ẹlẹ́gùn-ún, wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ṣugbọn ayé, ati ìtànjẹ ọrọ̀, ati ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ mìíràn gba ọkàn wọn, ó sì fún ọ̀rọ̀ náà pa, kò sì so èso. Àwọn mìíràn dàbí irúgbìn tí a fún sórí ilẹ̀ rere. Àwọn yìí ni ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí wọ́n gbà á, tí wọ́n sì so èso, òmíràn ọgbọọgbọn, òmíràn ọgọọgọta, òmíran ọgọọgọrun-un.” Jesu bi wọ́n pé, “Eniyan a máa gbé fìtílà wọlé kí ó fi igbá bò ó, tabi kí ó gbé e sí abẹ́ ibùsùn? Mo ṣebí lórí ọ̀pá fìtílà ni à ń gbé e kà. Nítorí kò sí ohun tí a fi pamọ́ tí a kò ní gbé jáde, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun ìkọ̀kọ̀ kan tí a kò ní yọ sí gbangba. Bí ẹnikẹ́ni bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́.” Ó tún wí fún wọn pé, “Ẹ fi ara balẹ̀ ro ohun tí ẹ bá gbọ́. Irú òfin tí ẹ bá fi ń ṣe ìdájọ́ fún eniyan ni a óo fi ṣe ìdájọ́ fún ẹ̀yin náà pẹlu èlé. Nítorí ẹni tí ó bá ní, a óo tún fi fún un sí i; ẹni tí kò bá sì ní, a óo gba ìba díẹ̀ tí ó ní lọ́wọ́ rẹ̀.” Ó tún wí pé, “Bí ìjọba Ọlọrun ti rí nìyí: ó dàbí ọkunrin kan tí ó gbin irúgbìn sí oko; ó ń sùn lálẹ́, ó ń jí ní òwúrọ̀, irúgbìn ń hù, ó ń dàgbà ní ọ̀nà tí ọkunrin náà kò mọ̀. Ilẹ̀ fúnra ara rẹ̀ ni ó ń mú kí ohun ọ̀gbìn so èso: yóo kọ́ rú ewé, lẹ́yìn náà èso rẹ̀ yóo gbó. Nígbà tí ó bá gbó tán, lẹsẹkẹsẹ ọkunrin náà yóo yọ dòjé jáde nítorí pé àkókò ìkórè ti dé.” Ó tún bèèrè pé, “Báwo ni à bá ṣe ṣe àlàyé ìjọba Ọlọrun, tabi òwe wo ni à bá fi ṣe àkàwé rẹ̀?” Ó ní, “Ó dàbí wóró musitadi kan tí a gbìn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni ó kéré jùlọ ninu gbogbo irúgbìn, ṣugbọn nígbà tí a gbìn ín, ó dàgbà, ó wá tóbi ju gbogbo ewébẹ̀ lọ, ó ní ẹ̀ka ńláńlá, àwọn ẹyẹ wá ń tẹ́ ìtẹ́ wọn sábẹ́ òjìji rẹ̀.” Pẹlu ọpọlọpọ irú òwe bẹ́ẹ̀ ni Jesu fi ń sọ̀rọ̀ ìyìn rere fún wọn, gẹ́gẹ́ bí òye wọn ti mọ láti lè gbọ́. Kì í bá wọn sọ̀rọ̀ láì lo òwe. Ṣugbọn nígbà tí ó bá ku òun ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, a máa túmọ̀ gbogbo rẹ̀ fún wọn. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí èbúté ní òdìkejì òkun.” Wọ́n bá fi àwọn eniyan sílẹ̀, wọ́n mú un lọ pẹlu wọn ninu ọkọ̀ tí ó wà. Àwọn ọkọ̀ mìíràn wà níbẹ̀ pẹlu. Ìjì líle kan bá dé, omi òkun bẹ̀rẹ̀ sí bì lu ọkọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí omi fi kún inú rẹ̀. Jesu wà ní ẹ̀yìn ọkọ̀, ó fi ìrọ̀rí kan rọrí, ó bá sùn lọ. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ jí i, wọ́n ní, “Olùkọ́ni, o kò tilẹ̀ bìkítà bí a bá ṣègbé sinu omi!” Ó bá dìde lójú oorun, ó bá afẹ́fẹ́ wí, ó wí fún òkun pé, “Pa rọ́rọ́.” Afẹ́fẹ́ bá rọlẹ̀. Ìdákẹ́rọ́rọ́ bá dé. Ó bá bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ṣe lójo bẹ́ẹ̀? Ẹ kò ì tíì ní igbagbọ sibẹ?” Ẹ̀rù ńlá bà wọ́n. Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bi ara wọn pé, “Ta ni èyí, tí afẹ́fẹ́ ati òkun ń gbọ́ràn sí lẹ́nu!” Jesu lọ sí òdìkejì òkun ní ilẹ̀ àwọn ará Geraseni. Bí ó ti jáde kúrò ninu ọkọ̀, ọkunrin wèrè kan wá pàdé rẹ̀ láti inú ibojì pàlàpálá àpáta. Ibojì náà ni ò fi ṣe ilé. Kò sí ẹni tí ó lè de wèrè náà mọ́lẹ̀; ẹ̀wọ̀n kò tilẹ̀ ṣe é fi dè é. Nítorí ní ọpọlọpọ ìgbà ni wọ́n kó ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ sí i lẹ́sẹ̀, tí wọ́n tún fi ẹ̀wọ̀n dè é lọ́wọ́. Ṣugbọn jíjá ni ó máa ń já ẹ̀wọ̀n, tí ó sì máa ń rún ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ tí wọ́n fi dè é. Kò sí ẹni tí ó lè fi agbára mú un kí ó fi ara balẹ̀. Tọ̀sán-tòru níí máa kígbe láàrin àwọn ibojì ati lórí òkè, a sì máa fi òkúta ya ara rẹ̀. Ṣugbọn nígbà tí ó rí Jesu lókèèrè, ó sáré, ó dọ̀bálẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó ké rara pé, “Kí ni ó pa tàwa-tìrẹ pọ̀, Jesu ọmọ Ọlọrun tí ó lógo jùlọ? Mo fi Ọlọrun bẹ̀ ọ́, má ṣe dá mi lóró.” (Nítorí Jesu tí ń sọ pé kí ẹ̀mí èṣù náà jáde kúrò ninu ọkunrin náà.) Jesu wá bi í pé, “Kí ni orúkọ rẹ?” Ó ní, “Ẹgbaagbeje ni mò ń jẹ́, nítorí a kò níye.” Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ Jesu títí pé kí ó má ṣe lé wọn jáde kúrò ní agbègbè ibẹ̀. Agbo ọ̀pọ̀ ẹlẹ́dẹ̀ kan wà níbẹ̀, wọ́n ń jẹ lẹ́bàá òkè. Àwọn ẹ̀mí èṣù náà bẹ̀ ẹ́ pé kí ó rán wọn sí ààrin ẹlẹ́dẹ̀ náà, kí wọ́n lè wọ inú wọn. Ó bá gbà bẹ́ẹ̀ fún wọn. Àwọn ẹ̀mí èṣù náà jáde lọ, wọ́n wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà bá tú pẹ̀ẹ́, wọ́n sáré láti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè lọ sí òkun, wọ́n bá rì sinu òkun. Wọ́n tó bí ẹgbaa (2,000). Àwọn olùtọ́jú wọn bá sálọ sí àwọn ìlú ati àwọn abúlé tí ó wà yíká láti ròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Àwọn eniyan bá wá fi ojú ara wọn rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n rí ọkunrin náà tí ó ti jẹ́ wèrè rí, tí ó ti ní ẹgbaagbeje ẹ̀mí èṣù, ó jókòó, ó wọ aṣọ, iyè rẹ̀ sì ti bọ̀ sípò. Ẹ̀rù ba àwọn eniyan tí ó rí i. Àwọn tí ọ̀rọ̀ náà ṣe ojú wọn ròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọkunrin náà ati àwọn ẹlẹ́dẹ̀. Àwọn eniyan bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ Jesu pé kí ó kúrò ní agbègbè wọn. Bí ó ti ń wọ ọkọ̀ ojú omi pada, ọkunrin tí ó ti jẹ́ wèrè rí yìí bẹ̀ ẹ́ pé kí ó jẹ́ kí òun máa bá a lọ. Ṣugbọn Jesu kọ̀ fún un, ó sọ fún un pé, “Lọ sí ilé rẹ, sọ́dọ̀ àwọn ẹbí rẹ, kí o sọ ohun tí Oluwa ti ṣe fún ọ ati bí ó ti ṣàánú rẹ.” Ọkunrin náà lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí ròyìn ohun tí Jesu ṣe fún un ní agbègbè Ìlú Mẹ́wàá, ẹnu sì ya gbogbo eniyan tí ó gbọ́. Nígbà tí Jesu tún rékọjá lọ sí òdìkejì òkun, ọpọlọpọ eniyan wọ́ jọ pọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀ lẹ́bàá òkun. Ọkunrin kan wà tí ń jẹ́ Jairu, aṣaaju kan ni ní ilé ìpàdé ibẹ̀. Nígbà tí ó rí Jesu, ó dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀ ẹ́. Ó ní, “Ọmọdebinrin mi ń kú lọ, wá gbé ọwọ́ lé e, kí ó lè yè.” Jesu bá bá a lọ. Bí ó ti ń lọ, ọpọlọpọ eniyan ń tẹ̀lé e, wọ́n ń fún un lọ́tùn-ún lósì. Obinrin kan wà láàrin wọn tí nǹkan oṣù rẹ̀ kọ̀ tí kò dá fún ọdún mejila. Ojú rẹ̀ ti rí oríṣìíríṣìí lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn. Gbogbo ohun ìní rẹ̀ ni ó ti run sórí àìsàn náà. Ṣugbọn kàkà kí ó sàn, ńṣe ni àìsàn náà túbọ̀ ń burú sí i. Nígbà tí obinrin náà gbọ́ nípa Jesu, ó gba ààrin àwọn eniyan dé ẹ̀yìn rẹ̀, ó bá fi ọwọ́ kan aṣọ rẹ̀, nítorí ó sọ ninu ara rẹ̀ pé, “Bí ó bá jẹ́ aṣọ rẹ̀ ni mo lè fi ọwọ́ kàn, ara mi yóo dá.” Lẹsẹkẹsẹ tí ó fọwọ́ kàn án ni ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ bá dá. Ó sì mọ̀ ninu ara rẹ̀ pé a ti mú òun lára dá ninu àìsàn náà. Lójú kan náà Jesu mọ̀ ninu ara rẹ̀ pé agbára ìwòsàn jáde lára òun. Ó bá yipada sí àwọn eniyan, ó bèèrè pé, “Ta ni fọwọ́ kàn mí láṣọ?” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “O rí i bí àwọn eniyan ti ń fún ọ lọ́tùn-ún lósì, o tún ń bèèrè pé ta ni fọwọ́ kàn ọ́?” Ṣugbọn Jesu ń wò yíká láti rí ẹni tí ó fọwọ́ kan aṣọ rẹ̀. Obinrin náà mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lára òun, ó bá yọ jáde. Ẹ̀rù bà á, ó ń gbọ̀n, ó bá wá kúnlẹ̀ níwájú Jesu, ó sọ gbogbo òtítọ́ ọ̀rọ̀ náà fún un. Jesu wí fún un pé, “Arabinrin, igbagbọ rẹ ti mú ọ lára dá. Máa lọ ní alaafia, o kò ní gbúròó àìsàn náà mọ́.” Kò tíì dákẹ́ ọ̀rọ̀ tí ń sọ, ni àwọn kan bá dé láti ilé olórí ilé ìpàdé tí Jesu ń bá lọ sílé, wọ́n ní, “Ọmọdebinrin rẹ ti kú, kí ni o tún ń yọ olùkọ́ni lẹ́nu sí?” Ṣugbọn Jesu kò pé òun gbọ́ ohun tí wọn ń sọ, ó wí fún ọkunrin náà pé, “Má bẹ̀rù, ṣá ti gbàgbọ́.” Kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tẹ̀lé òun àfi Peteru ati Jakọbu ati Johanu àbúrò Jakọbu. Nígbà tí wọ́n dé ilé olórí ilé ìpàdé náà, Jesu rí bí gbogbo ilé ti dàrú, tí ẹkún ati ariwo ń sọ gèè. Ó bá wọ inú ilé lọ, ó ní, “Kí ló dé tí ẹ fi ń kígbe, tí ẹ̀ ń sunkún bẹ́ẹ̀? Ọmọde náà kò kú; ó sùn ni.” Wọ́n bá ń fi ṣe yẹ̀yẹ́, ó bá lé gbogbo wọn jáde. Ó wá mú baba ati ìyá ọmọ náà pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí ó wà pẹlu rẹ̀, ó wọ yàrá tí ọmọde náà wà lọ. Ó bá fa ọmọde náà lọ́wọ́, ó wí fún un pé, “Talita kumi” ìtumọ̀ èyí tíí ṣe, “Ìwọ ọmọde yìí, mo wí fún ọ, dìde.” Lẹsẹkẹsẹ ọmọdebinrin náà dìde, ó bá ń rìn, nítorí ọmọ ọdún mejila ni. Ìyàlẹ́nu ńlá ni ó jẹ́ fún gbogbo wọn. Jesu wá kìlọ̀ fún wọn gan-an pé kí wọn má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀. Ó ní kí wọn wá oúnjẹ fún ọmọde náà kí ó jẹ. Jesu jáde kúrò níbẹ̀, ó lọ sí ìlú rẹ̀. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá a lọ. Nígbà tí ó di Ọjọ́ Ìsinmi, ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn eniyan ninu ilé ìpàdé. Ẹnu ya ọpọlọpọ àwọn tí ó gbọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀. Wọ́n ń wí pé, “Níbo ni eléyìí ti kọ́ ẹ̀kọ́? Irú ọgbọ́n wo ni ọgbọ́n tirẹ̀ yìí, tí iṣẹ́ ìyanu ń ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe? Ṣebí gbẹ́nàgbẹ́nà ni, ọmọ Maria, arakunrin Jakọbu, ati Juda, ati Simoni? Ṣebí àwọn arabinrin rẹ̀ nìwọ̀nyí lọ́dọ̀ wa yìí?” Wọ́n sì kọ̀ ọ́. Ṣugbọn Jesu wí fún wọn pé, “Kò sí wolii tí kò níyì, àfi ní ìlú ara rẹ̀, ati láàrin àwọn ará rẹ̀, ati ninu ẹbí rẹ̀.” Kò lè ṣe iṣẹ́ ìyanu níbẹ̀ àfi pé ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé àwọn aláìsàn bíi mélòó kan, a sì wò wọ́n sàn. Ẹnu yà á nítorí aigbagbọ wọn. Jesu ń káàkiri gbogbo àwọn abúlé tí ó wà yíká, ó ń kọ́ àwọn eniyan. Ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mejila, ó rán wọn lọ ní meji-meji, ó fi àṣẹ fún wọn lórí àwọn ẹ̀mí èṣù. Ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọn má mú ohunkohun lọ́wọ́ ní ọ̀nà àjò náà àfi ọ̀pá nìkan. Wọn kò gbọdọ̀ mú oúnjẹ, tabi igbá báárà lọ́wọ́, tabi kí wọn fi owó sinu àpò wọn. Kí wọn wọ bàtà, ṣugbọn kí wọn má wọ ẹ̀wù meji. Ó tún fi kún un fún wọn pé, “Ilékílé tí ẹ bá wọ̀, níbẹ̀ ni kí ẹ máa gbé títí ẹ óo fi kúrò ní ìlú náà. Ibikíbi tí wọn kò bá ti gbà yín, tí wọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ yín, ẹ jáde kúrò níbẹ̀, kí ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí láti kìlọ̀ fún wọn.” Bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila ti ń lọ, wọ́n ń waasu pé kí gbogbo eniyan ronupiwada. Wọ́n ń lé ọpọlọpọ ẹ̀mí èṣù jáde, wọ́n ń fi òróró pa ọpọlọpọ aláìsàn lára, wọ́n sì ń mú wọn lára dá. Hẹrọdu ọba gbọ́ nípa Jesu, nítorí òkìkí rẹ̀ kàn. Àwọn kan ń sọ pé, “Johanu Onítẹ̀bọmi ni ó jí dìde ninu òkú, òun ni ó jẹ́ kí ó lè máa ṣe iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀.” Ṣugbọn àwọn mìíràn ń wí pé, “Elija ni.” Àwọnmìíràn ní, “Wolii ni, bí ọ̀kan ninu àwọn wolii àtijọ́.” Ṣugbọn nígbà tí Hẹrọdu gbọ́, ó ní, “Johanu tí mo ti bẹ́ lórí ni ó jí dìde.” Nítorí Hẹrọdu kan náà yìí ni ó ranṣẹ lọ mú Johanu tí ó fi í sẹ́wọ̀n nítorí ọ̀ràn Hẹrọdiasi iyawo Filipi arakunrin Hẹrọdu tí Hẹrọdu gbà. Nítorí Johanu a máa wí fún Hẹrọdu pé, “Kò yẹ fún ọ láti gba iyawo arakunrin rẹ.” Nítorí náà Hẹrọdiasi ní Johanu sinu, ó fẹ́ pa á, ṣugbọn kò lè pa á, nítorí Hẹrọdu bẹ̀rù Johanu, nítorí ó mọ̀ pé olóòótọ́ eniyan ni ati pé kò ní àléébù. Nítorí náà ó dáàbò bò ó. Ọkàn Hẹrọdu a máa dàrú gidigidi nígbàkúùgbà tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ Johanu, sibẹ a máa fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Nígbà tí ó di ọjọ́ kan, Hẹrọdiasi rí àkókò tí ó wọ̀ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Hẹrọdu se àsè ọjọ́ ìbí rẹ̀, ó pe àwọn ìjòyè, àwọn ọ̀gágun, ati àwọn eniyan pataki ilẹ̀ Galili. Ọmọ Hẹrọdiasi obinrin bá wọlé, ó bọ́ sí agbo, ó bẹ̀rẹ̀ sí jó, inú Hẹrọdu ati ti àwọn tí ó wà níbi àsè náà dùn. Ọba sọ fún ọmọbinrin náà pé, “Bèèrè ohun tí o bá fẹ́, n óo fi í fún ọ.” Ó bá búra fún un pé, “N óo fún ọ ní ohunkohun tí o bá bèèrè, kì báà ṣe ìdajì ìjọba mi.” Ọmọbinrin náà bá lọ sí ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀, ó ní, “Kí ni kí n bèèrè?” Ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Bèèrè orí Johanu Onítẹ̀bọmi.” Ọmọbinrin náà yára lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, ó wí pé, “Mo fẹ́ kí o fún mi ní orí Johanu Onítẹ̀bọmi kíákíá, kí wọ́n fi àwo pẹrẹsẹ gbé e wá.” Inú ọba bàjẹ́ pupọ, ṣugbọn nítorí ó ti ṣe ìlérí pẹlu ìbúra lójú àwọn tí ó wà níbi àsè, kò fẹ́ kọ̀ fún un. Lẹsẹkẹsẹ ọba rán ọmọ-ogun kan, ó pàṣẹ fún un kí ó gbé orí Johanu wá. Ó bá lọ, ó bẹ́ ẹ lórí ninu ilé ẹ̀wọ̀n. Ó bá fi àwo pẹrẹsẹ gbé orí rẹ̀ wá, ó fi í fún ọmọbinrin náà. Ọmọbinrin náà bá gbé e lọ fún ìyá rẹ̀. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu gbọ́, wọ́n wá gbé òkú rẹ̀, wọ́n sin ín sinu ibojì. Àwọn aposteli Jesu pé jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ròyìn gbogbo nǹkan tí wọ́n ti ṣe ati bí wọ́n ti kọ́ àwọn eniyan. Ó bá wí fún wọn pé, “Ẹ wá kí á lọ sí ibìkan níkọ̀kọ̀, níbi tí kò sí eniyan, kí ẹ sinmi díẹ̀.” Nítorí ọpọlọpọ eniyan ni wọ́n ń lọ, tí wọn ń bọ̀, tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi sí àyè láti jẹun. Wọ́n bá bọ́ sinu ọkọ̀ ojú omi kan, wọ́n fẹ́ yọ́ lọ sí ibi tí kò sí eniyan. Ṣugbọn ọpọlọpọ eniyan rí wọn bí wọ́n ti ń lọ, wọ́n mọ̀ wọ́n, wọ́n bá fi ẹsẹ̀ rìn, wọ́n sáré láti inú gbogbo ìlú wọn lọ sí ibi tí ọkọ̀ darí sí, wọ́n sì ṣáájú wọn dé ibẹ̀. Nígbà tí Jesu jáde ninu ọkọ̀ ó rí ọpọlọpọ eniyan, àánú ṣe é nítorí wọ́n dàbí aguntan tí kò ní olùṣọ́. Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn ní ọpọlọpọ nǹkan. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá, wọ́n wí fún un pé, “Aṣálẹ̀ nìhín yìí, ilẹ̀ sì ń ṣú lọ. Jẹ́ kí àwọn eniyan túká, kí wọn lè lọ sí àwọn abà ati abúlé tí ó wà yíká láti ra oúnjẹ fún ara wọn.” Ṣugbọn Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni kí ẹ fún wọn ní ohun tí wọn óo jẹ.” Wọ́n ní, “Ṣé kí á wá lọ ra oúnjẹ igba owó fadaka ni, kí a lè fún wọn jẹ!” Ó bi wọ́n pé, “Ìba oúnjẹ wo ni ẹ ní? Ẹ lọ wò ó.” Lẹ́yìn tí wọ́n wádìí, wọ́n ní “Burẹdi marun-un ni ati ẹja meji.” Ó bá pàṣẹ fún wọn kí gbogbo àwọn eniyan jókòó ní ìṣọ̀wọ́, ìṣọ̀wọ́ lórí koríko. Wọ́n bá jókòó lọ́wọ̀ọ̀wọ́, ní ọgọọgọrun-un ati ní aadọtọọta. Jesu bá mú burẹdi marun-un ati ẹja meji náà, ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó dúpẹ́. Ó bá bu burẹdi náà, ó fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọn pín in fún àwọn eniyan. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó pín ẹja meji náà fún gbogbo wọn. Gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó. Wọ́n bá kó àjẹkù burẹdi ati ẹja jọ, ó kún agbọ̀n mejila. Iye àwọn ọkunrin tí ó jẹ oúnjẹ náà jẹ́ ẹgbẹẹdọgbọn (5000). Lẹsẹkẹsẹ ó ní kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ọkọ̀ ojú omi, kí wọn ṣiwaju rẹ̀ lọ sí òdìkejì òkun ní agbègbè Bẹtisaida. Lẹ́yìn náà ó ní kí àwọn eniyan túká. Nígbà tí ó ti dágbére fún wọn, ó lọ sí orí òkè, ó lọ gbadura. Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wà ninu ọkọ̀ ní ààrin òkun, òun nìkan ni ó kù lórí ilẹ̀. Ó rí i pé pẹlu ipá ni wọ́n fi ń wa ọkọ̀, nítorí afẹ́fẹ́ ṣọwọ́ òdì sí wọn. Ó tó bí agogo mẹta òru kí Jesu tó máa lọ sọ́dọ̀ wọn. Ó ń rìn lórí omi, ó fẹ́ kọjá lára wọn. Nígbà tí wọn rí i tí ó ń rìn lórí omi, wọ́n ṣebí iwin ni, wọ́n bá kígbe. Nítorí gbogbo wọn ni wọ́n rí i tí ẹ̀rù sì bà wọ́n. Ṣugbọn lójú kan náà ó fọhùn sí wọn, ó ní, “Ẹ fi ọkàn balẹ̀. Èmi ni. Ẹ má bẹ̀rù.” Ó bá wọ inú ọkọ̀ tọ̀ wọ́n lọ, afẹ́fẹ́ bá rọlẹ̀. Ẹnu yà wọ́n lọpọlọpọ, nítorí pé iṣẹ́ ìyanu ti burẹdi kò yé wọn, nítorí òpè ni wọ́n. Nígbà tí wọ́n la òkun já, wọ́n dé Genesarẹti, wọ́n bá gúnlẹ̀. Bí wọ́n ti jáde kúrò ninu ọkọ̀, lẹsẹkẹsẹ àwọn eniyan mọ̀ wọ́n. Wọ́n bá ń súré láti gbogbo àdúgbò ibẹ̀, wọ́n ń gbé àwọn aláìsàn wọn lórí ibùsùn wá sí ibikíbi tí wọn bá gbọ́ pé Jesu wà. Níbikíbi tí ó bá wọ̀, ìbáà ṣe ní abúlé tabi ninu ìlú, ní ìgbèríko, tabi ní ọjà, wọ́n ń gbé àwọn aláìsàn wá. Wọn a máa bẹ̀ ẹ́ pé kí wọn ṣá lè fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí ẹ̀wù rẹ̀. Gbogbo àwọn tí wọ́n fi ọwọ́ kàn án pátá ni ó mú lára dá. Àwọn Farisi ati àwọn amòfin kan tí wọ́n wá láti Jerusalẹmu péjọ sí ọ̀dọ̀ Jesu. Wọ́n rí ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tí wọn ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun, èyí ni pé, wọn kò wẹ ọwọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin. (Nítorí pé àwọn Farisi ati gbogbo àwọn Juu yòókù kò jẹ́ jẹun láì wẹ ọwọ́ ní ọ̀nà tí òfin là sílẹ̀; wọ́n ń tẹ̀lé àṣà ìbílẹ̀ wọn. Bí wọn bá ti ọjà dé, wọ́n kò jẹ́ jẹun láìjẹ́ pé wọ́n kọ́kọ́ wẹ̀. Ọpọlọpọ nǹkan mìíràn ni ó ti di àṣà wọn, gẹ́gẹ́ bíi fífọ àwo ìmumi, ìkòkò ìpọnmi ati àwọn àwo kòtò onídẹ.) Àwọn Farisi ati àwọn amòfin wá bi í pé, “Kí ló dé tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kò fi tẹ̀lé àṣà ìbílẹ̀, tí wọn ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun?” Jesu wí fún wọn pé, “Òtítọ́ ni Aisaya sọ ní àtijọ́ nípa ẹ̀yin àgàbàgebè, tí ó sì kọ ọ́ báyìí pé, ‘Ọlọrun wí pé: Ẹnu ni àwọn eniyan wọnyi fi ń yẹ́ mi sí, ṣugbọn ọkàn wọn jìnnà sí mi, asán ni sísìn tí wọn ń sìn mí, ìlànà eniyan ni wọ́n fi ń kọ́ni bí òfin Ọlọrun.’ “Ẹ fi àṣẹ Ọlọrun sílẹ̀, ẹ wá dìmọ́ àṣà eniyan.” Jesu tún wí fún wọn pé, “Òtítọ́ ni pé ẹ pa àṣẹ Ọlọrun tì, kí ẹ lè mú àṣẹ ìbílẹ̀ yín ṣẹ. Nítorí Mose wí pé, ‘Bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ’ ati pé, ‘Kí á pa ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ àbùkù sí baba tabi ìyá rẹ̀.’ Ṣugbọn ẹ̀yin wí pé, ‘Bí eniyan bá wí fún baba tabi ìyá rẹ̀ pé ohunkohun tí n bá fun yín, Kobani ni,’ (èyí ni pé ẹ̀bùn fún Ọlọrun ni), ẹ ti gbà pé ẹni bẹ́ẹ̀ kò ní ohunkohun í ṣe fún baba tabi ìyá rẹ̀ mọ́. Ẹ fi àṣà ìbílẹ̀ yín yí ọ̀rọ̀ Ọlọrun po. Ọpọlọpọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni ẹ tún ń ṣe.” Ó tún pe àwọn eniyan, ó ń wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ẹ fi etí sílẹ̀, kí ọ̀rọ̀ mi ye yín. Kò sí ohun kan láti òde wá tí ó wọ inú eniyan lọ tí ó lè sọ ọ́ di aláìmọ́. Ṣugbọn àwọn ohun tí ó ń jáde láti inú eniyan ni ó ń sọ ọ́ di aláìmọ́. [ Ẹni tí ó bá ní etí láti gbọ́ràn, kí ó gbọ́.”] Nígbà tí ó kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan, tí ó wọ inú ilé lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bi í ní ìtumọ̀ òwe yìí. Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin náà kò ní òye? Kò ye yín pé kì í ṣe nǹkan tí ó bá wọ inú eniyan lọ níí sọ eniyan di aláìmọ́? Nítorí kì í wọ inú ọkàn lọ, bíkòṣe inú ikùn, a sì tún jáde.” (Báyìí ni ó pe gbogbo oúnjẹ ní mímọ́.) Ó tún fi kún un pé, “Àwọn nǹkan tí ń jáde láti inú eniyan ni ó ń sọ ọ́ di aláìmọ́. Nítorí láti inú ọkàn eniyan ni ète burúkú ti ń jáde: ìṣekúṣe, olè jíjà, ìpànìyàn, àgbèrè, ojúkòkòrò, ìwà ìkà, ẹ̀tàn, ìwà wọ̀bìà, owú jíjẹ, ọ̀rọ̀ ìṣáátá, ìwà ìgbéraga, ìwà òmùgọ̀. Láti inú ni gbogbo àwọn nǹkan ibi wọnyi ti ń wá, àwọn ni ó ń sọ eniyan di aláìmọ́.” Láti ibẹ̀ Jesu gbéra, ó lọ sí agbègbè ìlú Tire, ó sì wọ̀ sí ilé kan. Kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀, ṣugbọn kò lè fi ara pamọ́. Obinrin kan tí ọdọmọbinrin rẹ̀ ní ẹ̀mí èṣù gbọ́ nípa rẹ̀. Lẹsẹkẹsẹ ó wá kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀. Ọmọ ìbílẹ̀ Giriki ni obinrin yìí, a bí i ní Fonike ní Siria. Ó ń bẹ̀ ẹ́ kí ó lé ẹ̀mí èṣù náà jáde kúrò ninu ọdọmọbinrin òun. Jesu wí fún un pé, “Jẹ́ kí àwọn ọmọ rí oúnjẹ jẹ yó ná, nítorí kò dára kí á mú oúnjẹ ọmọ kí á sọ ọ́ fún ajá.” Ṣugbọn obinrin náà dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, alàgbà, ṣugbọn àwọn ajá a máa jẹ ẹ̀rúnrún oúnjẹ àwọn ọmọ tí ó bá bọ́ sílẹ̀ láti orí tabili.” Jesu dá a lóhùn pé, “Nítorí gbolohun rẹ yìí, máa lọ sí ilé rẹ, ẹ̀mí èṣù náà ti jáde kúrò ninu ọmọ rẹ.” Ó bá pada lọ sí ilé rẹ̀, ó rí ọmọde náà tí ó dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn, tí ẹ̀mí burúkú náà ti jáde kúrò lára rẹ̀. Ó tún jáde kúrò ní agbègbè ìlú Tire, ó la ìlú Sidoni kọjá lọ sí òkun Galili ní ọ̀nà ààrin Ìlú Mẹ́wàá. Wọ́n wá gbé adití kan tí ń kólòlò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó fi ọwọ́ lé e. Ó bá mú un bọ́ sí apá kan, kúrò láàrin àwọn ọ̀pọ̀ eniyan, ó ti ìka rẹ̀ bọ ọkunrin náà létí, ó tutọ́, ó fi kan ahọ́n rẹ̀. Ó gbé ojú sí òkè ọ̀run, ó kẹ́dùn, ó bá ní, “Efata,” ìtumọ̀ èyí tí i ṣe, “Ìwọ, ṣí.” Etí ọkunrin náà bá ṣí, okùn ahọ́n rẹ̀ tú, ó bá ń sọ̀rọ̀ gaara. Jesu kìlọ̀ fún wọn pé kí wọn má wí fún ẹnikẹ́ni. Ṣugbọn bí ó ti ń kìlọ̀ fún wọn tó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ròyìn rẹ̀ tó. Ẹnu ya gbogbo wọn kọjá ààlà, wọ́n ń wí pé, “Ó ṣe ohun gbogbo dáradára: ó mú kí adití gbọ́ràn, ó mú kí odi sọ̀rọ̀.” Ní ọjọ́ kan, nígbà tí ọpọlọpọ eniyan tún wà lọ́dọ̀ Jesu, tí wọn kò rí nǹkan jẹ, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Àánú àwọn eniyan wọnyi ń ṣe mí, nítorí ó di ọjọ́ mẹta tí wọ́n ti wà pẹlu mi, wọn kò ní ohun tí wọn yóo jẹ mọ́. Bí mo bá ní kí wọn túká lọ sí ilé wọn ní ebi, yóo rẹ̀ wọ́n lọ́nà, nítorí àwọn mìíràn ninu wọn ti ọ̀nà jíjìn wá.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Níbo ni a óo ti rí ohun tí a óo fún gbogbo àwọn wọnyi jẹ ní aṣálẹ̀ yìí?” Jesu bi wọ́n pé, “Burẹdi mélòó ni ẹ ní?” Wọ́n ní, “Meje.” Ó bá pàṣẹ kí àwọn eniyan jókòó ní ilẹ̀. Ó mú burẹdi meje náà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó bù ú fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní kí wọn pín in fún àwọn eniyan. Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n tún ní àwọn ẹja kéékèèké díẹ̀. Ó gbadura sí i, ó ní kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pín in fún àwọn eniyan. Àwọn eniyan jẹ, wọ́n yó. Wọ́n bá kó ẹ̀rúnrún àjẹkù jọ, ó kún apẹ̀rẹ̀ ńlá meje. Àwọn eniyan tí wọn jẹun tó bí ẹgbaaji (4,000). Lẹ́yìn náà Jesu ní kí wọn túká. *** Lẹsẹkẹsẹ ó wọ inú ọkọ̀ ojú omi pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó bá lọ sí agbègbè Dalimanuta. Àwọn Farisi jáde lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń dán an wò nípa fífi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò, wọ́n ní kí ó fi àmì láti ọ̀run hàn wọ́n. Inú rẹ̀ bàjẹ́, ó ní, “Nítorí kí ni àwọn eniyan ṣe ń wá àmì lóde òní? Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé a kò ní fún wọn ní àmì kan.” Ó bá fi wọ́n sílẹ̀, ó tún wọ inú ọkọ̀ ojú omi, ó lọ sí òdìkejì òkun. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu gbàgbé láti mú burẹdi lọ́wọ́ àfi ọ̀kan ṣoṣo tí wọn ní ninu ọkọ̀ ojú omi. Jesu bá kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ kíyèsára kí ẹ sì ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisi ati ìwúkàrà Hẹrọdu.” Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Nítorí a kò ní burẹdi ni.” Nígbà tí Jesu mọ ohun tí wọn ń sọ, ó bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ̀ ń sọ láàrin ara yín pé nítorí ẹ kò ní burẹdi lọ́wọ́ ni? Ẹ kò ì tíì mọ̀ sibẹ, tabi òye kò ì tíì ye yín? Àṣé ọkàn yín le tóbẹ́ẹ̀? Ẹ ní ojú lásán ni, ẹ kò ríran? Ẹ ní etí lásán ni, ẹ kò fi gbọ́ràn? Ẹ kò ranti nígbà tí mo bu burẹdi marun-un fún ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) eniyan, agbọ̀n mélòó ni àjẹkù tí ẹ kó jọ?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Mejila.” Ó tún bi wọ́n pé, “Nígbà tí mo fi burẹdi meje bọ́ àwọn ẹgbaaji (4,000) eniyan, agbọ̀n ńlá mélòó ni àjẹkù tí ẹ kó jọ?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Meje.” Ó tún bi wọ́n pé, “Kò ì tíì ye yín sibẹ?” Wọ́n dé Bẹtisaida. Àwọn ẹnìkan mú afọ́jú kan wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń bẹ̀ ẹ́ pé kí ó fọwọ́ kàn án. Ó bá fa afọ́jú náà lọ́wọ́ jáde lọ sí ẹ̀yìn abúlé, ó tutọ́ sí i lójú. Ó bi í pé, “Ǹjẹ́ o rí ohunkohun?” Ọkunrin náà ríran bàìbàì, ó ní, “Mo rí àwọn eniyan tí ń rìn, ṣugbọn bí igi ni wọ́n rí lójú mi.” Lẹ́yìn náà Jesu tún fi ọwọ́ kàn án lójú. Ọkunrin náà tẹjú mọ́ àwọn nǹkan tí ó wà ní àyíká rẹ̀, ojú rẹ̀ sì bọ̀ sípò, ó wá rí gbogbo nǹkan kedere, títí kan ohun tí ó jìnnà. Jesu wí fún un pé, kí ó máa lọ sí ilé rẹ̀, kí ó má ṣe wọ inú abúlé lọ. Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jáde lọ sí àwọn abúlé tí ó wà lẹ́bàá ìlú Kesaria ti Filipi. Bí wọ́n ti ń lọ ní ọ̀nà, ó bi wọ́n pé, “Ta ni àwọn eniyan ń pè mí?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwọn kan ń pè ọ́ ní Johanu Onítẹ̀bọmi, àwọn mìíràn ní Elija ni ọ́, àwọn mìíràn tún ní ọ̀kan ninu àwọn wolii ni ọ́.” Ó wá bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ńkọ́, ta ni ẹ̀yin ń pè mí?” Peteru dá a lóhùn pé, “Ìwọ ni Kristi náà.” Ó bá kìlọ̀ fún wọn pé kí wọn má ṣe sọ fún ẹnikẹ́ni. Ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn pé, “Ọmọ-Eniyan níláti jìyà pupọ. Àwọn àgbà ati àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin yóo ta á nù, wọn yóo sì pa á, ṣugbọn lẹ́yìn ọjọ́ mẹta yóo jí dìde.” Ó ń sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn kedere. Nígbà náà ni Peteru mú un, ó bẹ̀rẹ̀ sí bá a wí. Ṣugbọn Jesu yipada sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó bá Peteru wí. Ó ní, “Kó ara rẹ kúrò níwájú mi, ìwọ Satani. Ìwọ kò kó ohun ti Ọlọrun lékàn àfi ti ayé.” Ó pe àwọn eniyan ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ máa tọ̀ mí lẹ́yìn, ó níláti gbàgbé ara rẹ̀, kí ó gbé agbelebu rẹ̀, kí ó wá máa tẹ̀lé mi. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là, yóo pàdánù rẹ̀. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nítorí mi ati nítorí ìyìn rere, yóo gba ẹ̀mí rẹ̀ là. Nítorí anfaani kí ni ó jẹ́ fún eniyan kí ó jèrè gbogbo dúkìá ayé yìí, ṣugbọn kí ó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀? Kí ni eniyan lè fi ṣe pàṣípààrọ̀ ẹ̀mí rẹ̀? Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá tijú èmi ati ọ̀rọ̀ mi ní àkókò burúkú yìí, tí àwọn eniyan kò ka nǹkan Ọlọrun sí, Ọmọ-Eniyan yóo tijú rẹ̀ nígbà tí ó bá dé ninu ògo Baba rẹ̀ pẹlu àwọn angẹli mímọ́.” Ó tún wí fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, àwọn kan wà ninu àwọn tí ó dúró níhìn-ín tí wọn kò ní kú títí wọn óo fi rí ìjọba Ọlọrun tí yóo dé pẹlu agbára.” Lẹ́yìn ọjọ́ mẹfa, Jesu mú Peteru ati Jakọbu ati Johanu lọ sí orí òkè gíga kan, àwọn mẹta yìí nìkan ni ó mú lọ. Ìrísí rẹ̀ bá yipada lójú wọn. Ẹ̀wù rẹ̀ ń dán, ó funfun láúláú, kò sí alágbàfọ̀ kan ní ayé tí ó lè fọ aṣọ kí ó funfun tóbẹ́ẹ̀. Wọ́n rí Elija pẹlu Mose tí wọn ń bá Jesu sọ̀rọ̀. Peteru wí fún Jesu pé, “Olùkọ́ni, ó dára tí a wà níhìn-ín. Jẹ́ kí á pàgọ́ mẹta, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mose ati ọ̀kan fún Elija.” Ẹ̀rù tí ó bà wọ́n pupọ kò jẹ́ kí ó mọ ohun tí ì bá wí. Ìkùukùu kan bá ṣíji bò wọ́n, ohùn kan bá wá láti inú ìkùukùu náà tí ó wí pé, “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹ máa gbọ́ tirẹ̀.” Lójijì, bí wọ́n ti wò yíká, wọn kò rí ẹnìkankan lọ́dọ̀ wọn mọ́, àfi Jesu nìkan. Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà, Jesu pàṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ ròyìn ohun tí wọ́n ti rí fún ẹnikẹ́ni títí òun, Ọmọ-Eniyan, yóo fi jí dìde kúrò ninu òkú. Wọ́n fi ọ̀rọ̀ náà sọ́kàn, wọ́n ń bá ara wọn jiyàn nípa ìtumọ̀ jíjí dìde kúrò ninu òkú. Wọ́n bá bi í léèrè pé, “Kí ló dé tí àwọn amòfin fi sọ pé Elija ni ó níláti kọ́ dé?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Elija ni ó níláti kọ́ dé láti mú ohun gbogbo bọ̀ sípò.” Ó wá bi wọ́n pé, “Báwo ni a ti ṣe kọ nípa Ọmọ-Eniyan pé ó níláti jìyà pupọ, kí a sì fi àbùkù kàn án?” Ó sì tún wí fún wọn pé, “Elija ti dé, wọ́n ti ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ sí i, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ nípa rẹ̀.” Nígbà tí Jesu dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó rí ọpọlọpọ eniyan pẹlu àwọn amòfin, wọ́n ti ń bá ara wọn jiyàn. Lẹsẹkẹsẹ bí gbogbo àwọn eniyan ti rí i, ẹnu yà wọ́n, wọ́n bá sáré lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń kí i. Ó bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ̀yin ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi ń jiyàn lé lórí?” Ẹnìkan ninu wọn bá dá a lóhùn pé, “Olùkọ́ni, ọmọ mi tí ẹ̀mí èṣù ti sọ di odi ni mo mú wá sí ọ̀dọ̀ rẹ. Níbikíbi tí ó bá ti dé sí i, ẹ̀mí èṣù yìí á gbé e ṣánlẹ̀, ọmọ náà yóo máa yọ ìfòòfó lẹ́nu, yóo wa eyín pọ̀, ara rẹ̀ yóo wá le gbandi. Mo sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ pé kí wọn lé ẹ̀mí náà jáde, ṣugbọn wọn kò lè ṣe é.” Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ìran alaigbagbọ yìí! N óo ti wà pẹlu yín pẹ́ tó? N óo ti fara dà á fun yín pẹ́ tó? Ẹ mú ọmọ náà wá.” Wọ́n bá mú un lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Nígbà tí ẹ̀mí burúkú yìí rí Jesu, ó mú kí gìrì ki ọmọ náà ní akọ, ó gbé e ṣánlẹ̀, ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí yí nílẹ̀, ó ń yọ ìfòòfó lẹ́nu. Jesu wá bi baba ọmọ náà pé, “Ó ti tó ìgbà wo tí irú èyí ti ń ṣe é?” Baba rẹ̀ dáhùn pé, “Láti kékeré ni.” Ó ní, “Nígbà pupọ ẹ̀mí náà á gbé e sọ sinu iná tabi sinu omi, kí ó lè pa á. Ṣugbọn bí ìwọ bá lè ṣe ohunkohun, ṣàánú wa kí o ràn wá lọ́wọ́.” Jesu wí fún un pé, “Ọ̀ràn bí èmi bá lè ṣe é kọ́ yìí, ohun gbogbo ni ó ṣeéṣe fún ẹni tí ó bá gbàgbọ́.” Lẹ́sẹ̀ kan náà baba ọmọ náà kígbe pé, “Mo gbàgbọ́; ràn mí lọ́wọ́ níbi tí igbagbọ mi kù kí ó tó.” Nígbà tí Jesu rí i pé àwọn ìjọ eniyan ń sáré bọ̀, ó bá ẹ̀mí èṣù náà wí, ó ní, “Ìwọ ẹ̀mí tí o jẹ́ kí ọmọ yìí ya odi, tí o sì di í létí, mo pàṣẹ fún ọ, jáde kúrò ninu rẹ̀, kí o má tún wọ inú rẹ̀ mọ́.” Ẹ̀mí náà bá kígbe, ó mú kí gìrì ki ọmọ náà ní akọ, ó sì jáde. Ọmọ náà wá dàbí ẹni tí ó kú, tóbẹ́ẹ̀ tí ọpọlọpọ ninu àwọn eniyan náà ń sọ pé ó ti kú. Ṣugbọn Jesu fà á lọ́wọ́, ó gbé e dìde, ọmọ náà bá nàró. Nígbà tí Jesu wọ inú ilé, tí ó ku òun ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n ń bi í pé, “Kí ló dé tí àwa kò fi lè lé ẹ̀mí náà jáde?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Irú èyí kò ṣe é lé jáde, àfi pẹlu adura [ati ààwẹ̀.”] Láti ibẹ̀ wọ́n jáde lọ, wọ́n ń la Galili kọjá. Jesu kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀, nítorí ó ń kọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ń wí fún wọn pé, “A óo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn eniyan lọ́wọ́, wọn yóo pa á, ṣugbọn nígbà tí wọ́n bá ti pa á tán, yóo jí dìde lẹ́yìn ọjọ́ mẹta.” Ṣugbọn ohun tí ó ń wí kò yé wọn, ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Nígbà tí wọ́n dé Kapanaumu, tí wọ́n wọ inú ilé, ó bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ̀ ń bá ara yín sọ lọ́nà?” Wọ́n bá dákẹ́ nítorí ní ọ̀nà, wọ́n ti ń bá ara wọn jiyàn lórí ta ni ó ṣe pataki jùlọ. Lẹ́yìn tí ó ti jókòó, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mejila, ó wí fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ jẹ́ ọ̀gá, ó níláti ṣe iranṣẹ fún gbogbo eniyan.” Ó bá fa ọmọde kan dìde ní ààrin wọn, ó gbé e sí ọwọ́ rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọ̀kan ninu àwọn ọmọ kékeré yìí nítorí orúkọ mi, èmi ni ó gbà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí, kì í ṣe èmi ni ó gbà, ṣugbọn ó gba ẹni tí ó rán mi wá sí ayé.” Johanu wí fún un pé, “Olùkọ́ni, a rí ẹnìkan tí ó ń fi orúkọ rẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ṣugbọn a gbìyànjú láti dá a lẹ́kun, nítorí kì í ṣe ara wa.” Ṣugbọn Jesu dáhùn pé, “Ẹ má ṣe dá a lẹ́kun, nítorí kò sí ẹni tí yóo fi orúkọ mi ṣe iṣẹ́ ìyanu tí yóo yára sọ ọ̀rọ̀ ibi nípa mi. Nítorí ẹni tí kò bá lòdì sí wa, tiwa ni. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fun yín ní omi mu nítorí tèmi, nítorí pé ẹ jẹ́ ti Kristi, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé yóo rí èrè rẹ̀ gbà. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú ọ̀kan ninu àwọn kéékèèké wọnyi tí ó gbà mí gbọ́ kọsẹ̀, ó sàn fún un kí á so ọlọ ńlá mọ́ ọn lọ́rùn, kí á gbé e sọ sinu òkun. Bí ọwọ́ rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù, ó sàn fún ọ kí o wọ inú ìyè pẹlu àléébù ara, jù pé kí o ní ọwọ́ mejeeji kí o wọ iná àjóòkú, [ níbi tí ìdin wọn kì í kú, tí iná ibẹ̀ kì í sì í kú.] Bí ẹsẹ̀ rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù, ó sàn fún ọ kí o jẹ́ ẹlẹ́sẹ̀ kan kí o sì wọ inú ìyè jù pé kí o ní ẹsẹ̀ mejeeji kí á sì sọ ọ́ sinu iná, [ níbi tí ìdin wọn kì í kú, tí iná ibẹ̀ kì í sì í kú.] Bí ojú rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ sọnù, ó sàn fún ọ kí o wọ ìjọba Ọlọrun pẹlu ojú kan jù pé kí o ní ojú mejeeji kí a sì sọ ọ́ sinu iná, níbi tí ìdin wọn kì í kú, tí iná ibẹ̀ kì í sì í kú. “Iyọ̀ níí sọ ẹbọ di mímọ́, bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó jẹ́ pé iná ni a óo fi sọ gbogbo eniyan di mímọ́. “Iyọ̀ dára, ṣugbọn bí iyọ̀ bá di òbu, báwo ni yóo ṣe tún lè dùn mọ́? “Ẹ ní iyọ̀ ninu ara yín, nígbà náà ni alaafia yóo wà láàrin yín.” Nígbà tí Jesu dìde kúrò níbẹ̀, ó lọ sí agbègbè Judia, ó rékọjá sí òdìkejì odò Jọdani. Ọpọlọpọ àwọn eniyan tún lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, ó tún ń kọ́ wọn. Àwọn Farisi bá jáde wá, wọ́n ń bi í bí ó bá tọ́ kí ọkunrin kọ iyawo rẹ̀ sílẹ̀. Wọ́n fi ìbéèrè yìí dán an wò ni. Ó dá wọn lóhùn pé, “Kí ni Mose pa láṣẹ fun yín?” Wọ́n dáhùn pé, “Mose yọ̀ǹda pé kí ọkọ kọ ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún iyawo rẹ̀, kí ó sì kọ̀ ọ́.” Ṣugbọn Jesu wí fún wọn pé, “Nítorí oríkunkun yín ni Mose fi kọ òfin yìí. Láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé, takọ-tabo ni Ọlọrun dá wọn. Nítorí èyí ni ọkunrin yóo ṣe fi baba ati ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóo wá fi ara mọ́ iyawo rẹ̀; àwọn mejeeji yóo wá di ọ̀kan. Wọn kì í tún ṣe ẹni meji mọ́ bíkòṣe ọ̀kan. Nítorí náà ohun tí Ọlọrun bá ti so pọ̀, kí ẹnikẹ́ni má ṣe yà á.” Nígbà tí wọ́n pada wọ inú ilé, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bi í nípa ọ̀rọ̀ náà. Ó bá wí fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ iyawo rẹ̀ sílẹ̀, tí ó gbé ẹlòmíràn ní iyawo, ó ṣe àgbèrè sí iyawo rẹ̀ àkọ́kọ́. Bí ó bá sì jẹ́ pé obinrin ni ó kọ ọkọ rẹ̀, tí ó fẹ́ ọkọ mìíràn, òun náà ṣe àgbèrè.” Àwọn kan gbé àwọn ọmọ kéékèèké wá sọ́dọ̀ rẹ̀ kí ó lè fi ọwọ́ kàn wọ́n. Ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bá àwọn tí ó gbé wọn wá wí. Nígbà tí Jesu rí i inú bí i: ó wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọde wá sí ọ̀dọ̀ mi, ẹ má dá wọn dúró, nítorí ti irú wọn ni ìjọba Ọlọrun. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ẹnikẹ́ni tí kò bá gba ìjọba Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ọmọde, kò ní wọ ìjọba ọ̀run.” Nígbà náà ni Jesu gbé àwọn ọmọde náà lọ́wọ́, ó gbé ọwọ́ lé wọn, ó sì súre fún wọn. Nígbà tí Jesu jáde, bí ó ti ń lọ lọ́nà, ọkunrin kan sáré tọ̀ ọ́ lọ, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bi í pé, “Olùkọ́ni rere, kí ni kí n ṣe kí n lè jogún ìyè ainipẹkun?” Ṣugbọn Jesu wí fún un pé, “Kí ló dé tí o fi pè mí ní ẹni rere? Kò sí ẹni rere kan, àfi Ọlọrun nìkan. Ṣé o mọ àwọn òfin: má paniyan, má ṣe àgbèrè, má jalè, má jẹ́rìí èké, má rẹ́nijẹ, bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ?” Ọkunrin náà dáhùn pé, “Olùkọ́ni, láti ìgbà tí mo ti wà ní ọdọmọkunrin ni mo ti ń pa gbogbo nǹkan wọnyi mọ́.” Jesu wá tẹjú mọ́ ọn, ó fi tìfẹ́tìfẹ́ wò ó, ó wí fún un pé, “Nǹkankan ló kù kí o ṣe: lọ ta ohun gbogbo tí o ní, kí o pín owó rẹ̀ fún àwọn aláìní, o óo wá ní ọrọ̀ ní ọ̀run; lẹ́yìn náà wá, kí o máa tẹ̀lé mi.” Ṣugbọn ojú ọkunrin náà fàro nígbà tí ó gbọ́ bẹ́ẹ̀, ó bá jáde lọ pẹlu ìbànújẹ́, nítorí pé ọrọ̀ tí ó ní pọ̀. Jesu bá wo ọ̀tún, ó wo òsì, ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Yóo ṣòro pupọ fún àwọn ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọrun!” Ẹnu ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nítorí gbolohun yìí. Ṣugbọn Jesu tún wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ọmọde, yóo ṣòro pupọ láti wọ ìjọba Ọlọrun! Ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ kọjá, jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọrun!” Ẹnu ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pupọ. Wọ́n ń bá ara wọn sọ pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ta ni yóo là?” Jesu tẹjú mọ́ wọn, ó wí pé, “Kò ṣeéṣe fún eniyan, ṣugbọn ti Ọlọrun kò rí bẹ́ẹ̀, nítorí pé, kò sí ohun tí Ọlọrun kò lè ṣe.” Peteru bẹ̀rẹ̀ sí wí fún un pé, “Wò ó ná, a ti fi ohun gbogbo sílẹ̀ láti tọ̀ ọ́ lẹ́yìn!” Jesu dáhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, kò sí ẹnìkan tí ó fi ilé tabi arakunrin tabi arabinrin, tabi ìyá, tabi baba, tabi ọmọ, tabi ilẹ̀, sílẹ̀ nítorí mi ati nítorí ìyìn rere, tí kò ní rí ilé, arakunrin ati arabinrin, ìyá ati ọmọ, ati ilẹ̀ gbà ní ọgọrun-un ìlọ́po ní ìgbà ìsinsìnyìí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé pẹlu inúnibíni ni, yóo sì tún rí ìyè ainipẹkun ní ayé tí ń bọ̀. Ṣugbọn ọpọlọpọ tí ó jẹ́ ẹni iwájú yóo di èrò ẹ̀yìn, àwọn èrò ẹ̀yìn yóo wá di ẹni iwájú.” Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, tí wọn ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu, Jesu ṣáájú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ̀lé e. Ẹnu ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ẹ̀rù sì ba àwọn eniyan tí wọ́n tẹ̀lé e. Ó bá tún pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila sí apá kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí òun fún wọn. Ó ní, “Lílọ ni à ń lọ sí Jerusalẹmu yìí, a óo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin lọ́wọ́. Wọn yóo dá a lẹ́bi ikú, wọn yóo sì fi lé àwọn tí kì í ṣe Juu lọ́wọ́. Wọn yóo fi ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n yóo tutọ́ sí i lára, wọn yóo nà án, wọn yóo sì pa á. Ṣugbọn lẹ́yìn ọjọ́ mẹta yóo jí dìde.” Nígbà náà ni Jakọbu ati Johanu, àwọn ọmọ Sebede, wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n wí fún un pé, “Olùkọ́ni, a fẹ́ kí o ṣe ohunkohun tí a bá bèèrè lọ́wọ́ rẹ fún wa.” Jesu bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ fẹ́ kí n ṣe fun yín?” Wọ́n ní, “Gbà fún wa pé, nígbà tí ó bá di ìgbà ìgúnwà rẹ, kí ọ̀kan ninu wa jókòó ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún rẹ, kí ẹnìkejì jókòó ní ẹ̀gbẹ́ òsì rẹ.” Ṣugbọn Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin kò mọ ohun tí ẹ̀ ń bèèrè. Ṣé ẹ lè mu ninu ife ìrora tí èmi yóo mu, tabi kí ojú yín rí irú ìṣòro tí ojú mi yóo rí?” Wọ́n wí fún un pé, “Àwa lè ṣe é.” Ṣugbọn Jesu wí fún wọn pé, “Ninu irú ife ìrora tí n óo mu ẹ̀yin náà yóo mu, irú ìṣòro tí ojú mi yóo rí, tiyín náà yóo sì rí i. Ṣugbọn ní ti jíjókòó ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún ati ẹ̀gbẹ́ òsì mi, kì í ṣe tèmi láti fún ẹnikẹ́ni, ipò wọnyi wà fún àwọn tí Ọlọrun ti pèsè wọn sílẹ̀ fún.” Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́wàá yòókù gbọ́, inú bẹ̀rẹ̀ sí bí wọn sí Jakọbu ati Johanu. Ni Jesu bá pè wọ́n, ó wí fún wọn pé, “Ẹ mọ̀ pé àwọn aláṣẹ láàrin àwọn alaigbagbọ a máa jẹ ọlá lórí wọn, àwọn eniyan ńláńlá ninu wọn a sì máa lo agbára lórí wọn, ṣugbọn tiyín kò gbọdọ̀ rí bẹ́ẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ jẹ́ pataki láàrin yín níláti jẹ́ iranṣẹ yín; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fẹ́ jẹ́ aṣaaju ninu yín níláti máa ṣe ẹrú gbogbo yín. Nítorí Ọmọ-Eniyan pàápàá kò wá pé kí eniyan ṣe iranṣẹ fún un, ó wá láti ṣe iranṣẹ ni, ati láti fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà fún ọpọlọpọ eniyan.” Wọn dé Jẹriko. Bí Jesu pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ati ogunlọ́gọ̀ eniyan ti ń jáde kúrò ní Jẹriko, Batimiu afọ́jú, ọmọ Timiu, jókòó lẹ́bàá ọ̀nà, ó ń ṣagbe. Nígbà tí ó gbọ́ pé Jesu ará Nasarẹti ni ó dé, ó bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pé, “Jesu! Ọmọ Dafidi! Ṣàánú mi!” Ọpọlọpọ eniyan ń bá a wí pé kí ó panu mọ́. Ṣugbọn sibẹ ó túbọ̀ ń kígbe pé, “Ọmọ Dafidi! Ṣàánú mi.” Jesu bá dúró, ó ní, “Ẹ pè é wá.” Wọ́n wá wí fún afọ́jú náà pé, “Ṣe ara gírí, dìde, ó ń pè ọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni ọkunrin náà bọ́ aṣọ rẹ̀ sọ sí apá kan, ó fò sókè, ó bá lọ sí ọ̀dọ̀ Jesu. Jesu bi í pé, “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe fún ọ?” Afọ́jú náà dáhùn pé, “Olùkọ́ni, mo fẹ́ tún ríran ni.” Jesu bá wí fún un pé, “Máa lọ, igbagbọ rẹ ti mú ọ lára dá.” Lójú kan náà, afọ́jú náà bá ríran, ó bá ń bá Jesu lọ ní ọ̀nà. Nígbà tí wọ́n súnmọ́ Jerusalẹmu, nítòsí Bẹtifage ati Bẹtani, ní orí Òkè Olifi, ó rán meji ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀; ó sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí abúlé tí ẹ̀ ń wò ní ọ̀kánkán yìí, bí ẹ bá ti wọ inú rẹ̀, ẹ óo rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí ẹnikẹ́ni kò gùn rí, tí wọ́n so mọ́ èèkàn, ẹ tú u, kí ẹ fà á wá. Bí ẹnikẹ́ni bá bi yín pé, ‘Kí ló dé tí ẹ̀ ń tú u?’ Kí ẹ dáhùn pé, ‘Oluwa fẹ́ lò ó ni, lẹsẹkẹsẹ tí ó bá ti lò ó tán yóo dá a pada sibẹ.’ ” Wọ́n lọ, wọ́n rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà tí a so ní ẹnu ìlẹ̀kùn lóde, lẹ́bàá títì, wọ́n bá tú u. Àwọn kan tí wọ́n ti jókòó níbẹ̀ bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ̀ ń tú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́?” Wọ́n bá dá wọn lóhùn gẹ́gẹ́ bí Jesu ti wí fún wọn. Àwọn eniyan náà sì yọ̀ǹda fún wọn. Wọ́n bá fa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà wá sí ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n tẹ́ aṣọ wọn sí orí rẹ̀, Jesu bá gùn un. Ọpọlọpọ eniyan tẹ́ aṣọ wọn sí ọ̀nà, àwọn mìíràn tẹ́ ẹ̀ka igi tí wọ́n ya ní pápá. Àwọn tí ó ń lọ ní iwájú ati àwọn tí ó ń bọ̀ ní ẹ̀yìn ń kígbe pé, “Hosana! Olùbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ ní orúkọ Oluwa. Ibukun ni ìjọba tí ń bọ̀, ìjọba Dafidi baba ńlá wa. Hosana ní òkè ọ̀run!” Nígbà tí ó wọ Jerusalẹmu, ó wọ àgbàlá Tẹmpili, ó wo ohun gbogbo yíká. Nítorí ọjọ́ ti lọ, ó jáde lọ sí Bẹtani pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila. Ní ọjọ́ keji, bí wọ́n ti ń jáde kúrò ní Bẹtani, ebi ń pa á. Ó rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan tí ó ní ewé lókèèrè, ó bá lọ wò ó bí yóo rí èso lórí rẹ̀. Nígbà tí ó dé ìdí rẹ̀ kò rí ohunkohun àfi ewé, nítorí kò ì tíì tó àkókò èso. Jesu wí fún igi náà pé, “Kí ẹnikẹ́ni má rí èso jẹ lórí rẹ mọ́ lae!” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbọ́. Nígbà tí wọ́n dé Jerusalẹmu, Jesu wọ àgbàlá Tẹmpili lọ, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn tí wọn ń tà ati àwọn tí wọn ń rà jáde. Ó ti tabili àwọn onípàṣípààrọ̀ owó ṣubú, ó da ìsọ̀ àwọn tí ń ta ẹyẹlé rú. Kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gbé ohunkohun la àgbàlá Tẹmpili kọjá. Ó ń kọ́ wọn pé, “Kò ha wà ninu àkọsílẹ̀ pé, ‘Ilé adura fún gbogbo orílẹ̀-èdè ni a óo máa pe ilé mi?’ Ṣugbọn ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibi tí àwọn ọlọ́ṣà ń sápamọ́ sí!” Nígbà tí àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin gbọ́, wọ́n ń wá ọ̀nà tí wọn yóo fi pa á. Ṣugbọn wọ́n bẹ̀rù rẹ̀, nítorí ìyàlẹ́nu ni ẹ̀kọ́ rẹ̀ jẹ́ fún gbogbo eniyan. Nígbà tí ọjọ́ rọ̀ Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jáde kúrò ní ìlú. Nígbà tí ó di òwúrọ̀, bí wọ́n ti ń kọjá lọ, wọ́n rí i tí igi ọ̀pọ̀tọ́ àná ti gbẹ patapata láti orí dé gbòǹgbò. Peteru wá ranti ọ̀rọ̀ àná. Ó wí fún Jesu pé, “Olùkọ́ni, wo igi ọ̀pọ̀tọ́ tí o fi gégùn-ún, ó ti gbẹ!” Jesu dáhùn, ó wí fún wọn pé, “Ẹ ní igbagbọ ninu Ọlọrun; mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, bí ẹnikẹ́ni bá wí fún òkè yìí pé, ‘ṣídìí kúrò níbi tí o wà, kí o bọ́ sí inú òkun,’ tí kò bá ṣiyèméjì, ṣugbọn tí ó gbàgbọ́ pé, ohun tí òun wí yóo rí bẹ́ẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún un. Nítorí èyí, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé, ohun gbogbo tí ẹ bá bèèrè ninu adura, ẹ gbàgbọ́ pé ẹ ti rí i gbà, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fun yín. Nígbà tí ẹ bá dìde dúró láti gbadura, ẹ dáríjì ẹnikẹ́ni tí ẹ bá ní ohunkohun ninu sí, kí Baba yín ọ̀run lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín. [ Bí ẹ kò bá dárí ji eniyan, Baba yín ọ̀run kò ní dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.”] Wọ́n tún wá sí Jerusalẹmu. Bí Jesu ti ń rìn kiri ninu Tẹmpili, àwọn olórí alufaa, ati àwọn amòfin, ati àwọn àgbà wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Wọ́n ń bi í pé, “Irú àṣẹ wo ni o fi ń ṣe nǹkan wọnyi? Ta ni ó fún ọ ní àṣẹ tí o fi ń ṣe wọ́n?” Jesu dá wọn lóhùn, ó ní, “N óo bi yín léèrè ọ̀rọ̀ kan, ẹ dá mi lóhùn, èmi náà óo wá sọ irú àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọnyi. Ìrìbọmi tí Johanu ń ṣe, láti ọ̀run ni ó ti gba àṣẹ ni, tabi láti ọwọ́ eniyan? Ẹ dá mi lóhùn.” Nígbà náà ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn jiyàn pé, “Bí a bá wí pé, ‘Láti ọ̀run ni,’ yóo sọ pé, ‘Kí ló dé tí ẹ kò fi gbà á gbọ́?’ Àbí kí a wí pé, ‘Láti ọwọ́ eniyan ni?’ ” Wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan nítorí gbogbo eniyan ni ó gbà pé wolii tòótọ́ ni Johanu. Wọ́n bá dá Jesu lóhùn pé, “Àwa kò mọ̀.” Nígbà náà ni Jesu sọ fún wọn pé, “Èmi náà kò ní sọ irú àṣẹ tí mo fi ń ṣe àwọn nǹkan wọnyi fun yín.” Jesu bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Ọkunrin kan gbin àjàrà sinu oko kan, ó sì ṣe ọgbà yí i ká. Ó wa ihò ìfúntí sí ibẹ̀, ó kọ́ ilé-ìṣọ́, ó gba àwọn alágbàro tí yóo máa mú ninu èso àjàrà fi ṣe owó ọ̀yà wọn. Lẹ́yìn náà ó lọ sí ìdálẹ̀. Nígbà tí ó tó àkókò, ó rán ẹrú rẹ̀ kan lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn alágbàro náà pé, kí ó lọ gbà ninu èso àjàrà wá lọ́wọ́ wọn. Ṣugbọn nínà ni wọ́n nà án, wọ́n bá lé e pada ní ọwọ́ òfo. Ó tún rán ẹrú mìíràn lọ sí ọ̀dọ̀ wọn. Wọ́n lu òun lórí ní àlùbẹ́jẹ̀, wọ́n sì dójú tì í. Nígbà tí ó rán ẹrú mìíràn lọ, pípa ni wọ́n pa á. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe sí ọpọlọpọ àwọn ẹrú mìíràn, wọ́n lu àwọn kan, wọ́n pa àwọn mìíràn. Ó wá ku ẹnìkan tíí ṣe àyànfẹ́ ọmọ rẹ̀. Òun ni ó rán sí wọn gbẹ̀yìn, ó ní, ‘Wọn yóo bu ọlá fún ọmọ mi.’ Ṣugbọn àwọn alágbàro náà wí láàrin ara wọn pé, ‘Àrólé rẹ̀ nìyí, ẹ jẹ́ kí á pa á, kí ogún rẹ̀ jẹ́ tiwa.’ Nígbà náà ni wọ́n mú un, wọ́n pa á, wọ́n bá wọ́ ọ jù sẹ́yìn ọgbà àjàrà. “Kí ni ẹni tí ó ni ọgbà àjàrà náà yóo ṣe? Yóo wá, yóo pa àwọn alágbàro wọ̀n-ọn-nì, yóo sì fi ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàro mìíràn. Ẹ kò ì tíì kà ninu Ìwé Mímọ́, pé, ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀ ni ó di pataki igun ilé. Iṣẹ́ Oluwa ni èyí, Ìyanu ni ó jẹ́ ní ojú wa.’ ” Àwọn olórí alufaa, àwọn amòfin ati àwọn àgbà ń wá ọ̀nà láti mú un, nítorí wọ́n mọ̀ pé àwọn ni ó pa òwe yìí mọ́, ṣugbọn wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan. Wọ́n bá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bá tiwọn lọ. Wọ́n rán àwọn kan ninu àwọn Farisi ati àwọn ọ̀rẹ́ Hẹrọdu sí i láti lọ gbọ́ tẹnu rẹ̀. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, “Olùkọ́ni, sọ fún wa, ṣé ó tọ̀nà pé kí á máa san owó-orí fún Kesari ni, àbí kò tọ̀nà?” Ṣugbọn Jesu mọ àgàbàgebè wọn, ó wí fún wọn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń dẹ mí? Ẹ mú owó fadaka kan wá fún mi kí n rí i.” Wọ́n fún un ní ọ̀kan. Ó wá bi wọ́n pé, “Àwòrán ati àkọlé ta ni ó wà ní ara rẹ̀ yìí?” Wọ́n ní, “Ti Kesari ni.” Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ fi nǹkan tí ó bá jẹ́ ti Kesari fún Kesari, ohun tí ó bá sì jẹ́ ti Ọlọrun, ẹ fi fún Ọlọrun.” Ẹnu yà wọ́n pupọ sí ìdáhùn rẹ̀. Ní àkókò náà, àwọn Sadusi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. (Àwọn Sadusi ni wọ́n ní kò sí ohun tí ń jẹ́ ajinde òkú.) Wọ́n ní, “Olùkọ́ni, Mose kọ òfin kan fún wa pé bí ọkunrin kan bá kú, tí ó fi aya sílẹ̀, tí kò bá ní ọmọ, kí àbúrò rẹ̀ ṣú aya rẹ̀ lópó kí ó lè ní ọmọ ní orúkọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò meje kan wà, èyí ekinni fẹ́ aya, ó kú láì ní ọmọ, Ekeji ṣú aya rẹ̀ lópó, ṣugbọn òun náà kú láì ní ọmọ. Ẹkẹta náà kú láì ní ọmọ. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn mejeeje ṣá ṣe kú láì ní ọmọ. Ní ìgbẹ̀yìn gbogbo wọn, obinrin náà kú. Nígbà tí ó bá di ọjọ́ ajinde, iyawo ta ni obinrin yìí yóo jẹ́, nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn mejeeje ni ó ti fi ṣe aya?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ti ṣìnà patapata! Àṣé ẹ kò mọ Ìwé Mímọ́ tabi agbára Ọlọrun? Nítorí nígbà tí àwọn òkú bá jinde, kò sí pé à ń gbé iyawo tabi à ń fa obinrin fún ọkọ, ṣugbọn bí àwọn angẹli ọ̀run ni wọn yóo rí. Nípa ti pé a óo jí àwọn òkú dìde tabi a kò ní jí wọn, ẹ kò ì tíì kà ninu Ìwé Mose, níbi ìtàn ìgbẹ́ tí iná ń jó, bí Ọlọrun ti wí fún Mose pé, ‘Èmi ni Ọlọrun Abrahamu ati Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu?’ Èyí ni pé Ọlọrun kì í ṣe Ọlọrun àwọn òkú bíkòṣe ti àwọn alààyè. Nípa ìbéèrè yìí, ẹ ti ṣìnà patapata.” Amòfin kan lọ sí ọ̀dọ̀ Jesu, ó gbọ́ bí wọn tí ń fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀, ó wòye pé Jesu dá wọn lóhùn dáradára. Ó bá bèèrè pé, “Èwo ni ó ṣe pataki jùlọ ninu gbogbo òfin?” Jesu dáhùn pé, “Èyí tí ó ṣe pataki jùlọ nìyí, ‘Gbọ́, Israẹli, Oluwa Ọlọrun wa nìkan ni Oluwa. Kí ìwọ fẹ́ràn Oluwa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn rẹ, ati pẹlu gbogbo ẹ̀mí rẹ ati pẹlu gbogbo iyè inú rẹ, ati pẹlu gbogbo agbára rẹ.’ Èyí tí ó ṣìkejì ni pé, ‘Kí ìwọ fẹ́ràn ẹnìkejì rẹ bí o ti fẹ́ràn ara rẹ.’ Kò sí òfin mìíràn tí ó tóbi ju èyí lọ.” Amòfin náà wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ gan-an ni, Olùkọ́ni. Òtítọ́ ni o sọ pé, ‘Ọlọrun kan ni ó wà. Kò sí òmíràn lẹ́yìn rẹ̀’; ati pé, ‘Kí á fẹ́ràn ẹnìkejì wa bí a ti fẹ́ràn ara wa’ tayọ gbogbo ẹbọ sísun ati ẹbọ yòókù.” Nígbà náà ni Jesu ṣe akiyesi pé ó fi òye sọ̀rọ̀, ó wí fún un pé, “Ìwọ kò jìnnà sí ìjọba Ọlọrun.” Kò sì sí ẹnìkan tí ó ní ìgboyà láti tún bi í ní ìbéèrè kankan mọ́. Bí Jesu ti ń kọ́ àwọn eniyan ninu Tẹmpili, ó bèèrè pé, “Báwo ni àwọn amòfin ṣe wí pé ọmọ Dafidi ni Kristi? Dafidi fúnrarẹ̀ wí nípa ìmísí Ẹ̀mí Mímọ́ pé, ‘Oluwa wí fún Oluwa mi pé: Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi títí n óo fi fi àwọn ọ̀tá rẹ sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ.’ Nígbà tí Dafidi fúnrarẹ̀ pè é ní ‘Oluwa,’ báwo ni ó ti ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀?” Pẹlu ayọ̀ ni ọpọlọpọ eniyan ń fetí sí ẹ̀kọ́ rẹ̀. Jesu ń sọ ninu ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé, “Ẹ ṣọ́ra fún àwọn amòfin tí wọ́n fẹ́ràn ati máa wọ agbádá ńlá káàkiri òde, kí eniyan máa kí wọn ní ọjà, ati láti gba ìjókòó pataki ní ilé ìpàdé. Wọ́n fẹ́ràn ipò ọlá nínú sinagọgu ati ní ibi àsè. Wọ́n a máa jẹ ilé àwọn opó run. Wọ́n a máa gbadura gígùn nítorí àṣehàn. Ìdájọ́ tí wọn yóo gbà yóo le pupọ.” Bí Jesu ti jókòó lọ́kàn-ánkán àpótí owó, ó ń wò bí ọpọlọpọ eniyan ti ń dá owó sinu àpótí. Ọpọlọpọ àwọn ọlọ́rọ̀ ń dá owó pupọ sinu àpótí owó. Nígbà náà ni talaka opó kan wá, ó dá eépìnnì meji tí ó jẹ́ kọbọ kan sinu àpótí. Jesu wá tọ́ka sí èyí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní, “Mo ń wí fun yín gbangba pé opó talaka yìí dá owó ju gbogbo àwọn tí ó dá owó sinu àpótí lọ. Nítorí ninu ọpọlọpọ ọrọ̀ ni àwọn yòókù ti mú ohun tí wọ́n dá, ṣugbọn òun, ninu àìní rẹ̀, ó dá gbogbo ohun tí ó ní, àní gbogbo ohun tí ó fi ẹ̀mí tẹ̀.” Bí ó ti ń jáde kúrò ninu Tẹmpili, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Olùkọ́ni, wo òkúta wọnyi ati ilé yìí, wò ó bí wọn ti tóbi tó!” Jesu wí fún un pé, “O rí ilé yìí bí ó ti tóbi tó? Kò ní sí òkúta kan lórí ekeji níhìn-ín tí a kò ní wó lulẹ̀.” Nígbà tí Jesu jókòó ní orí Òkè Olifi, tí ó dojú kọ Tẹmpili, Peteru, Jakọbu, Johanu ati Anderu bi í níkọ̀kọ̀ pé, “Sọ fún wa, nígbà wo ni àwọn nǹkan wọnyi yóo ṣẹ ati pé kí ni àmì tí yóo hàn kí gbogbo àwọn nǹkan wọnyi tó rí bẹ́ẹ̀?” Ni Jesu bá tẹnu bọ̀rọ̀, ó ní, “Ẹ ṣọ́ra, kí ẹnikẹ́ni má ṣe tàn yín jẹ. Ọpọlọpọ yóo wá ní orúkọ mi tí wọ́n yóo wí pé àwọn ni Kristi. Wọn yóo tan ọpọlọpọ jẹ. Ṣugbọn nígbà tí ẹ bá gbọ́ nípa oríṣìíríṣìí ogun nítòsí ati ní ọ̀nà jíjìn, ẹ má ṣe dààmú, bẹ́ẹ̀ ni ó níláti rí, ṣugbọn òpin ayé kò tíì dé. Nítorí orílẹ̀-èdè yóo gbé ogun ti orílẹ̀-èdè, ìjọba yóo dìde sí ìjọba, ilẹ̀ yóo mì tìtì ní oríṣìíríṣìí ìlú, ìyàn yóo mú ní ọpọlọpọ ilẹ̀. Ìbẹ̀rẹ̀ ìrora nìwọ̀nyí. “Ṣugbọn ẹ̀yin fúnra yín, ẹ kíyèsára. Wọn yóo fà yín lọ siwaju àwọn ìgbìmọ̀. Wọn yóo lù yín ninu àwọn ilé ìpàdé. Wọn yóo mu yín lọ siwaju àwọn aláṣẹ ati àwọn ọba nítorí mi kí ẹ lè jẹ́rìí ìyìn rere fún wọn. Ṣugbọn a níláti kọ́kọ́ waasu ìyìn rere fún orílẹ̀-èdè gbogbo ná. Nígbà tí wọn bá mu yín lọ sí ibi ìdájọ́, ẹ má ṣe da ara yín láàmú nípa ohun tí ẹ óo sọ, ṣugbọn ohun tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá fun yín ní wakati kan náà ni kí ẹ sọ, nítorí kì í ṣe ẹ̀yin ni ó ń sọ̀rọ̀ bíkòṣe Ẹ̀mí Mímọ́. Àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò yóo ṣe ikú pa ara wọn; bẹ́ẹ̀ ni baba yóo ṣe sí ọmọ rẹ̀, àwọn ọmọ yóo tàpá sí àwọn òbí wọn, wọn yóo sì pa wọ́n. Gbogbo eniyan ni yóo kórìíra yín nítorí orúkọ mi. Ṣugbọn ẹni tí ó bá forítì í títí dé òpin, òun ni a óo gbàlà. “Ṣugbọn nígbà tí ẹ bá rí ẹ̀gbin burúkú náà tí ó dúró níbi tí kò yẹ— (kí ó yé ẹni tí ń ka ìwé yìí)— nígbà náà, kí àwọn tí ó wà ní ilẹ̀ Judia sálọ sí orí òkè. Nígbà tí ẹni tí ó wà ní òkè ilé bá sọ̀kalẹ̀, kí ó má ṣe wọ ilé lọ láti mú ohunkohun jáde. Kí alágbàro ní oko má ṣe dúró mú ẹ̀wù rẹ̀ tí ó bọ́ sílẹ̀. Ọjọ́ ìṣòro ni ọjọ́ náà yóo jẹ́ fún àwọn aboyún ati àwọn tí ó ń fún ọmọ lọ́mú ní àkókò náà. Kí ẹ gbadura kí ó má jẹ́ àkókò tí òtútù mú pupọ. Nítorí ìpọ́njú yóo wà ní àkókò náà, irú èyí tí kò sí rí láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé, láti ìgbà tí Ọlọrun ti dá ohun gbogbo títí di àkókò yìí, kò sì ní sí irú rẹ̀ mọ́ lae. Bí kò bá jẹ́ pé Oluwa dín àkókò náà kù, ẹ̀dá kankan kì bá tí kù láàyè. Ṣugbọn nítorí àwọn àyànfẹ́ tí Ọlọrun yàn, ó dín àkókò rẹ̀ kù. “Bí ẹnikẹ́ni bá wí fun yín pé. ‘Wo Kristi níhìn-ín,’ tabi ‘Wò ó lọ́hùn-ún,’ ẹ má gbàgbọ́. Nítorí àwọn Kristi èké ati àwọn wolii èké yóo dìde, wọn yóo máa ṣe iṣẹ́ àmì ati iṣẹ́ ìyanu láti tan eniyan jẹ. Wọn óo tan àwọn àyànfẹ́ pàápàá jẹ, bí ó bá ṣeéṣe. Ṣugbọn ẹ̀yin, ní tiyín, ẹ ṣọ́ra. Mo ti sọ ohun gbogbo fun yín tẹ́lẹ̀. “Ní àkókò náà, lẹ́yìn ìpọ́njú yìí oòrùn yóo ṣókùnkùn, òṣùpá kò ní tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀. Àwọn ìràwọ̀ yóo máa já bọ́ láti ojú ọ̀run, a óo wá mi gbogbo àwọn ogun ọ̀run. Nígbà náà ni wọn yóo rí Ọmọ-Eniyan tí yóo máa bọ̀ ninu awọsanma pẹlu agbára ńlá ati ògo. Yóo wá rán àwọn angẹli láti lọ kó àwọn àyànfẹ́ jọ láti igun mẹrẹẹrin ayé, láti òpin ayé títí dé òpin ọ̀run. “Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ lára igi ọ̀pọ̀tọ́. Nígbà tí ẹ̀ka rẹ̀ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ, tí ó rú ewé, ẹ mọ̀ pé àkókò ẹ̀ẹ̀rùn súnmọ́ ìtòsí. Bákan náà nígbà tí ẹ bá rí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọnyi, kí ẹ mọ̀ pé Ọmọ-Eniyan wà nítòsí, ó fẹ́rẹ̀ dé. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, àwọn eniyan ìran yìí kò ní tíì kú tán tí gbogbo nǹkan wọnyi yóo fi ṣẹ. Ọ̀run ati ayé yóo kọjá lọ, ṣugbọn ọ̀rọ̀ mi kò ní kọjá lọ. “Ṣugbọn ní ti ọjọ́ ati wakati náà, kò sí ẹni tí ó mọ̀, àwọn angẹli kò mọ̀, Ọmọ pàápàá kò mọ̀, àfi Baba. Ẹ ṣọ́ra, ẹ máa fojú sọ́nà nítorí ẹ kò mọ wakati náà. Ó dàbí kí ọkunrin kan máa lọ sí ìdálẹ̀, kí ó fi ilé rẹ̀ sílẹ̀, kí ó fi àṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀, kí ó fi iṣẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan fún un, kí ó wá pàṣẹ fún olùṣọ́nà pé kí ó ṣọ́nà. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ máa ṣọ́nà nítorí ẹ kò mọ ìgbà tí baálé ilé náà yóo dé: bí ní ìrọ̀lẹ́ ni, tabi ní ọ̀gànjọ́, tabi ní àkùkọ ìdájí, tabi ní àfẹ̀mọ́jú. Bí ó bá dé lójijì, kí ó má baà ba yín lójú oorun. Ohun tí mò ń wí fun yín ni mò ń wí fún gbogbo eniyan: ẹ máa ṣọ́nà.” Nígbà tí Àjọ̀dún Ìrékọjá ati ti Àìwúkàrà ku ọ̀tunla, àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin ń wá ọ̀nà tí wọn yóo fi rí Jesu mú, kí wọ́n pa á. Nítorí wọ́n ń wí pé, “Kí ó má jẹ́ àkókò àjọ̀dún, kí rògbòdìyàn má baà bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn eniyan.” Nígbà tí Jesu wà ní Bẹtani, bí ó ti jókòó tí ó fẹ́ máa jẹun ní ilé Simoni tí ó dẹ́tẹ̀ nígbà kan rí, obinrin kan wọlé wá tí ó mú ìgò ojúlówó òróró ìpara olóòórùn dídùn kan tí ó ní iye lórí lọ́wọ́. Ó fọ́ ìgò náà, ó bá tú òróró inú rẹ̀ sí Jesu lórí. Ṣugbọn inú bí àwọn kan níbẹ̀, wọ́n ń sọ̀ láàrin ara wọn pé, “Kí ló dé tí a fi ń fi òróró yìí ṣòfò báyìí? Bí a bá tà á, ìbá tó nǹkan bí ọọdunrun (300) owó fadaka, à bá sì fún àwọn talaka.” Báyìí ni wọ́n ń fi ohùn líle bá obinrin náà wí. Ṣugbọn Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, kí ni ẹ̀ ń yọ ọ́ lẹ́nu sí? Ohun rere ni ó ṣe sí mi. Nítorí ìgbà gbogbo ni ẹ ní àwọn talaka láàrin yín, nígbàkúùgbà tí ẹ bá fẹ́, ẹ lè ṣe nǹkan fún wọn; ṣugbọn kì í ṣe ìgbà gbogbo ni èmi yóo máa wà láàrin yín. Ó ti ṣe ohun tí ó lè ṣe: ó fi òróró kun ara mi ní ìpalẹ̀mọ́ ìsìnkú mi. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, a óo máa sọ ohun tí obinrin yìí ṣe ní ìrántí rẹ̀ níbikíbi tí a bá ń waasu ìyìn rere ní gbogbo ayé.” Judasi Iskariotu, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila, bá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa, ó lọ fi Jesu lé wọn lọ́wọ́. Nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tí ó bá wá, inú wọn dùn, wọ́n bá ṣe ìlérí láti fún un ní owó. Judasi wá ń wá àkókò tí ó wọ̀ láti fi Jesu lé wọn lọ́wọ́. Ní ọjọ́ kinni Àjọ̀dún Àìwúkàrà, ní ọjọ́ tí wọn máa ń pa aguntan láti ṣe Àjọ̀dún Ìrékọjá, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu bi í pé, “Níbo ni o fẹ́ kí á tọ́jú fún ọ láti jẹ àsè Ìrékọjá?” Ó bá rán meji ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sí inú ìlú, ọkunrin kan tí ó ru ìkòkò omi yóo pàdé yín, ẹ tẹ̀lé e. Kí ẹ sọ fún baálé ilé tí ó bá wọ̀ pé, ‘Olùkọ́ni wí pé yàrá wo ni ààyè wà fún mi, níbi tí èmi ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi ti lè jẹ àsè Ìrékọjá?’ Yóo fi yàrá ńlá kan hàn yín, ní òkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì, tí wọn ti tọ́jú sílẹ̀. Níbẹ̀ ni kí ẹ ṣe ètò sí.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà bá lọ, wọ́n wọ inú ìlú, wọ́n rí ohun gbogbo bí Jesu ti sọ fún wọn; wọ́n sì tọ́jú gbogbo nǹkan fún àsè Ìrékọjá. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, Jesu wá sibẹ pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila. Bí wọ́n ti jókòó tí wọn ń jẹun, Jesu ní, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ọ̀kan ninu yín tí ń bá mi jẹun nisinsinyii ni yóo fi mí lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́.” Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí dààmú, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń bèèrè pé, “Àbí èmi ni?” Ṣugbọn ó wí fún wọn pé, “Ọ̀kan ninu ẹ̀yin mejeejila ni, tí ó ń fi òkèlè run ọbẹ̀ pẹlu mi ninu àwo kan náà. Nítorí Ọmọ-Eniyan ń lọ gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀, ṣugbọn ẹni tí yóo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ gbé! Ìbá sàn fún un bí a kò bá bí i.” Bí wọ́n ti ń jẹun, Jesu mú burẹdi, ó gbadura sí i, ó bù ú, ó fún wọn. Ó ní, “Ẹ gbà, èyí ni ara mi.” Ó tún mú ife, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó bá gbé e fún wọn. Gbogbo wọn mu ninu rẹ̀. Ó wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi tí a fi dá majẹmu, ẹ̀jẹ̀ tí a ta sílẹ̀ fún ọpọlọpọ eniyan. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé n kò ní mu ninu èso àjàrà mọ́ títí di ọjọ́ tí n óo mu ún ní ọ̀tun ninu ìjọba Ọlọrun.” Lẹ́yìn tí wọ́n kọ orin tán, wọ́n jáde lọ sí Òkè Olifi. Jesu bá sọ fún wọn pé, “Gbogbo yín ni ẹ óo pada lẹ́yìn mi, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, ‘Ọwọ́ yóo tẹ olùṣọ́-aguntan, àwọn aguntan yóo bá fọ́nká,’ Ṣugbọn lẹ́yìn tí a bá ti jí mi dìde, n óo ṣiwaju yín lọ sí Galili.” Ṣugbọn Peteru wí fún un pé, “Bí gbogbo eniyan bá pada lẹ́yìn rẹ, èmi kò ní pada.” Jesu wí fún un pé, “Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, ní alẹ́ yìí kí àkùkọ tó kọ ní ẹẹmeji, ìwọ náà yóo sẹ́ mi ní ẹẹmẹta.” Ṣugbọn Peteru tún tẹnu mọ́ ọn pé, “Bí ó bá kan ọ̀ràn pé kí n bá ọ kú, sibẹ n kò ní sẹ́ ọ!” Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yòókù ń wí. Wọ́n dé ibìkan tí wọn ń pè ní Gẹtisemani. Ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jókòó níhìn-ín nígbà tí mo bá lọ gbadura.” Ó wá mú Peteru, Jakọbu ati Johanu pẹlu rẹ̀. Àyà bẹ̀rẹ̀ sí pá a, ó bẹ̀rẹ̀ sí dààmú. Ó wí fún wọn pé, “Ọkàn mi bàjẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí mo fẹ́rẹ̀ lè kú. Ẹ dúró níhìn-ín kí ẹ máa ṣọ́nà.” Ó bá lọ sí iwájú díẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó ń gbadura pé bí ó bá ṣeéṣe kí àkókò yìí kọjá lórí òun. Ó ní, “Baba, Baba, ohun gbogbo ṣeéṣe fún ọ. Mú kí ife kíkorò yìí kọjá kúrò lórí mi. Ṣugbọn ìfẹ́ tìrẹ ni kí o ṣe, kì í ṣe ìfẹ́ tèmi.” Ó pada lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mẹta, ó rí i pé wọ́n ti sùn lọ! Ó wí fún Peteru pé, “Simoni, ò ń sùn ni? O kò lè ṣọ́nà fún wakati kan péré? Gbogbo yín, ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ tún máa gbadura, kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdánwò. Ẹ̀mí fẹ́ ṣe é, ṣugbọn ara kò lágbára.” Ó tún lọ gbadura, ó sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan náà bíi ti àkọ́kọ́. Ó tún wá, ó rí i pé wọ́n tún ń sùn, nítorí pé oorun ń kùn wọ́n pupọ. Wọn kò wá mọ ìdáhùn tí wọn ì bá fi fún un mọ́. Ó pada wá ní ẹẹkẹta, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ ṣì wà níbi tí ẹ̀ ń sùn, tí ẹ̀ ń gbádùn ìsinmi yín? Àbùṣe bùṣe! Àkókò náà tó. Wọn yóo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́. Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí á lọ. Ẹni tí yóo fi mí fún àwọn ọ̀tá ti súnmọ́ tòsí.” Bí Jesu ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Judasi, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila dé, pẹlu àwọn eniyan tí ó mú idà ati kùmọ̀ lọ́wọ́. Wọ́n wá láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin ati àwọn àgbà. Ẹni tí ó fi í fún àwọn ọ̀tá ti fi àmì fún wọn. Ó ní, “Ẹni tí mo bá kí, tí mo fi ẹnu kàn ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ni ọkunrin náà. Ẹ mú un, kí ẹ fà á lọ, ẹ má jẹ́ kí ó bọ́.” Lẹsẹkẹsẹ bí ó ti dé, Judasi lọ sí ọ̀dọ̀ Jesu, ó kí i, ó ní, “Olùkọ́ni!” Ó sì da ẹnu dé e ní ẹ̀rẹ̀kẹ́. Àwọn tí ó bá a wá bá ṣùrù mọ́ Jesu, wọ́n mú un. Ṣugbọn ọ̀kan ninu àwọn tí ó dúró fa idà yọ, ó fi ṣá ẹrú Olórí Alufaa, ó bá gé e létí. Jesu bá sọ fún wọn pé, “Ẹ mú idà ati kùmọ̀ lọ́wọ́ láti wá mú mi bí ẹni pé ẹ̀ ń bọ̀ wá mú ọlọ́ṣà? Lojoojumọ ni mo wà pẹlu yín ninu Tẹmpili tí mò ń kọ́ àwọn eniyan, ẹ kò ṣe mú mi nígbà náà. Ṣugbọn kí àkọsílẹ̀ lè ṣẹ ni èyí ṣe rí bẹ́ẹ̀.” Nígbà náà ni Gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá fi í sílẹ̀, wọ́n bá sálọ. Ọdọmọkunrin kan tí ó jẹ́ pé aṣọ funfun nìkan ni ó dà bo ara ń tẹ̀lé e. Nígbà tí wọ́n gbá a mú, ó fi aṣọ ìbora rẹ̀ sílẹ̀, ó bá sálọ níhòòhò. Wọ́n mú Jesu lọ sí ọ̀dọ̀ Olórí Alufaa, gbogbo àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ati àwọn amòfin wá péjọ sibẹ. Peteru wà ní òkèèrè, ó ń tẹ̀lé e títí ó fi wọ agbo-ilé Olórí Alufaa, ó bá jókòó pẹlu àwọn iranṣẹ, wọ́n jọ ń yá iná. Àwọn olórí alufaa ati gbogbo Ìgbìmọ̀ ń wá ẹ̀rí tí ó lòdì sí Jesu, kí wọ́n baà lè pa á, ṣugbọn wọn kò rí. Nítorí ọpọlọpọ ní ń jẹ́rìí èké sí i, ṣugbọn ẹ̀rí wọn kò bá ara wọn mu. Àwọn kan wá dìde, wọ́n ń jẹ́rìí èké sí i pé, “A gbọ́ nígbà tí ó ń wí pé, ‘Èmi yóo wó Tẹmpili tí eniyan kọ́ yìí, láàrin ọjọ́ mẹta, èmi óo gbé òmíràn dìde tí eniyan kò kọ́.’ ” Sibẹ ẹ̀rí wọn kò bá ara wọn mu. Nígbà náà ni Olórí Alufaa dìde láàrin wọn, ó bi Jesu pé, “Ìwọ kò fèsì rárá?” Ṣugbọn ó sá dákẹ́ ni, kò fèsì kankan. Olórí Alufaa tún bi í pé, “Ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Olùbùkún?” Jesu dáhùn pé, “Èmi ni. Ẹ óo rí Ọmọ-Eniyan tí ó jókòó lórí ìtẹ́ pẹlu agbára Ọlọrun, tí ìkùukùu yóo sì máa gbé e bọ̀ wá.” Olórí Alufaa bá fa ẹ̀wù rẹ̀ ya, ó ní, “Ẹlẹ́rìí wo ni a tún ń wá? Ẹ ti gbọ́ tí ó sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọrun! Kí ni ẹ wí?” Gbogbo wọn bá dá a lẹ́bi, wọ́n ní ikú ni ó tọ́ sí i. Àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí tutọ́ sí i lára. Wọ́n fi aṣọ bò ó lójú, wọ́n wá ń sọ ọ́ ní ẹ̀ṣẹ́. Wọ́n sọ fún un pé, “Sọ ẹni tí ó lù ọ́ fún wa, wolii!” Àwọn iranṣẹ wá ń gbá a létí bí wọn ti ń mú un lọ sí àtìmọ́lé. Nígbà tí Peteru wà ní ìsàlẹ̀ ní agbo-ilé, ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹbinrin Olórí Alufaa dé. Nígbà tí ó rí Peteru tí ó ń yáná, ó tẹjú mọ́ ọn, ó ní, “Ìwọ náà wà pẹlu Jesu ará Nasarẹti.” Ṣugbọn Peteru sẹ́, ó ní, “Èmi kò mọ̀... Ohun tí ò ń sọ kò yé mi rárá!” Ó wá jáde lọ sí apá ẹnu ọ̀nà agbo-ilé. Bẹ́ẹ̀ ni àkùkọ kan bá kọ. Iranṣẹbinrin náà tún bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn tí ó dúró pé, “Ọkunrin yìí wà ninu wọn!” Ṣugbọn ó tún sẹ́. Nígbà tí ó ṣe díẹ̀ síi àwọn tí ó dúró sọ fún Peteru pé, “Dájúdájú, o wà ninu wọn nítorí ará Galili ni ọ́.” Peteru bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣépè, ó bá ń búra pé, “N kò mọ ọkunrin tí ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí.” Lẹsẹkẹsẹ, àkùkọ kọ ní ẹẹkeji. Peteru wá ranti ọ̀rọ̀ tí Jesu sọ fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ ní ẹẹmeji, ìwọ yóo sẹ́ mi ní ẹẹmẹta!” Orí Peteru wú, ó bá bú sẹ́kún. Gbàrà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn olórí alufaa pẹlu àwọn àgbà ati àwọn amòfin ati gbogbo Ìgbìmọ̀ yòókù forí-korí, wọ́n de Jesu, wọ́n bá fà á lọ láti fi lé Pilatu lọ́wọ́ fún ìdájọ́. Pilatu bi Jesu pé, “Ṣé ìwọ ni ọba àwọn Juu?” Jesu dá a lóhùn pé, “O ti fi ẹnu ara rẹ sọ ọ́.” Àwọn olórí alufaa ń fi ẹ̀sùn pupọ kàn án. Pilatu bá tún bi í pé, “O kò sì fèsì rárá? Ìwọ kò gbọ́ bí wọ́n ti ń fi oríṣìíríṣìí ẹ̀sùn kàn ọ́ ni?” Ṣugbọn Jesu kò tún dá a lóhùn rárá mọ́, èyí mú kí ẹnu ya Pilatu. Ní ọdọọdún, ni àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá, Pilatu a máa dá ẹlẹ́wọ̀n kan tí wọ́n bá bẹ̀bẹ̀ fún sílẹ̀. Ẹnìkan wà tí ó ń jẹ́ Baraba, tí ó wà ninu ẹ̀wọ̀n pẹlu àwọn ọlọ̀tẹ̀ kan tí wọ́n pa eniyan ní àkókò ọ̀tẹ̀. Àwọn eniyan bá gòkè tọ Pilatu lọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀ ẹ́ pé kí ó ṣe bí ó ti máa ń ṣe fún wọn. Pilatu wá bi wọ́n pé, “Ẹ fẹ́ kí n dá ọba àwọn Juu sílẹ̀ fun yín bí?” Nítorí ó mọ̀ pé àwọn olórí alufaa ń jowú Jesu, wọ́n sì ń ṣe kèéta rẹ̀, ni wọ́n ṣe fà á wá siwaju òun. Ṣugbọn àwọn olórí alufaa rú àwọn eniyan sókè pé Baraba ni kí ó kúkú dá sílẹ̀ fún wọn. Pilatu tún bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ fẹ́ kí n ṣe sí ẹni tí ẹ̀ ń pè ní ọba àwọn Juu?” Nígbà náà ni gbogbo wọn kígbe pé, “Kàn án mọ́ agbelebu!” Ṣugbọn Pilatu bi wọ́n pé, “Nítorí kí ni? Nǹkan burúkú wo ni ó ṣe?” Ṣugbọn wọ́n sá tún kígbe pé, “Kàn án mọ́ agbelebu!” Pilatu bá dá Baraba sílẹ̀ fún wọn kí ó lè baà tẹ́ wọn lọ́rùn. Lẹ́yìn tí ó ti ní kí wọ́n na Jesu tán, ó bá fà á fún wọn láti kàn mọ́ agbelebu. Àwọn ọmọ-ogun bá mú un lọ sí inú agbo-ilé tí ààfin gomina wà. Wọ́n pe gbogbo àwọn ọmọ-ogun yòókù, wọ́n wọ̀ ọ́ ní aṣọ àlàárì, wọ́n wá fi ẹ̀gún hun adé, wọ́n fi dé e lórí. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí kí i pé, “Kabiyesi! Ọba àwọn Juu!” Wọ́n ń lù ú ní igi lórí, wọ́n ń tutọ́ sí i lára, wọ́n wá ń kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n ń júbà yẹ̀yẹ́. Nígbà tí wọ́n ti fi ṣe ẹlẹ́yà tán, wọ́n bọ́ aṣọ àlàárì kúrò ní ara rẹ̀, wọ́n fi aṣọ tirẹ̀ wọ̀ ọ́, wọ́n bá fà á jáde láti lọ kàn án mọ́ agbelebu. Bí ọkunrin kan tí ń jẹ́ Simoni, ará Kirene, baba Alẹkisanderu ati Rufọsi, ti ń ti ọ̀nà ìgbèríko bọ̀, bí ó ti ń kọjá lọ, wọ́n fi tipátipá mú un láti gbé agbelebu Jesu. Wọ́n wá mú Jesu lọ sí ibìkan tí à ń pè ní Gọlgọta (ìtumọ̀ èyí tíí ṣe “Ibi Agbárí”). Wọ́n fún un ní ọtí tí wọ́n ti po òjíá mọ́, ṣugbọn kò gbà á. Wọ́n bá kàn án mọ́ agbelebu. Wọ́n ṣẹ́ gègé lórí aṣọ rẹ̀ láti mọ èyí tí yóo kan ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe pín àwọn aṣọ náà mọ́ ara wọn lọ́wọ́. Ní agogo mẹsan-an òwúrọ̀ ni wọ́n kàn án mọ́ agbelebu. Àkọlé orí agbelebu tí wọ́n kọ, tí ó jẹ́ ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án ni: “Ọba àwọn Juu.” Ní àkókò kan náà, wọ́n kan àwọn ọlọ́ṣà meji kan mọ́ agbelebu, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, ọ̀kan ní ọwọ́ òsì rẹ̀. [ Báyìí ni àkọsílẹ̀ kan ṣẹ tí ó wí pé, “A kà á kún àwọn arúfin.”] Àwọn tí ń kọjá lọ ń sọ ìsọkúsọ sí i, wọ́n ń já apá mọ́nú, wọ́n ń wí pé, “Kò tán an! Ìwọ tí yóo wó Tẹmpili, tí yóo tún kọ́ ọ ní ọjọ́ mẹta, gba ara rẹ là, sọ̀kalẹ̀ láti orí agbelebu.” Bákan náà ni àwọn olórí alufaa pẹlu àwọn amòfin ń fi ṣe ẹlẹ́yà láàrin ara wọn, wọ́n ń wí pé, “Àwọn ẹlòmíràn ni ó le gbà là, kò lè gba ara rẹ̀ là. Kí Kristi ọba Israẹli sọ̀kalẹ̀ láti orí agbelebu nisinsinyii, kí á rí i, kí á lè gbàgbọ́.” Àwọn tí a kàn mọ́ agbelebu pẹlu rẹ̀ náà ń bu ẹ̀tẹ́ lù ú. Láti agogo mejila ọ̀sán ni òkùnkùn ti bo gbogbo ilẹ̀, títí di agogo mẹta ọ̀sán. Nígbà tí ó di agogo mẹta ọ̀sán, Jesu kígbe tòò, ó ní, “Eloi, Eloi, lema sabakitani?” Ìtumọ̀ èyí ni, “Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀?” Nígbà tí àwọn kan ninu àwọn tí ó dúró níbẹ̀ gbọ́, wọ́n ń wí pé, “Ẹ gbọ́! Ó ń pe Elija!” Ẹnìkan bá sáré, ó ti kinní kan bíi kànìnkànìn bọ inú ọtí kíkan, ó fi sí orí ọ̀pá láti fún un mu, ó ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á máa wò ó bí Elija yóo wá gbé e sọ̀kalẹ̀!” Ṣugbọn Jesu kígbe tòò, ó mí kanlẹ̀ ó bá dákẹ́. Aṣọ ìkélé tí ó wà ninu Tẹmpili bá ya sí meji láti òkè dé ilẹ̀. Nígbà tí ọ̀gágun tí ó dúró lọ́kàn-ánkán rẹ̀ rí bí ó ti dákẹ́ lẹ́yìn tí ó ti kígbe, ó ní, “Dájúdájú, ọmọ Ọlọrun ni ọkunrin yìí.” Àwọn obinrin kan wà ní òkèèrè tí wọn ń wo gbogbo ohun tí ń ṣẹlẹ̀. Ninu wọn ni Maria Magidaleni wà, ati Maria ìyá Jakọbu kékeré ati ìyá Josẹfu, ati Salomi. Àwọn wọnyi ti ń tẹ̀lé e láti ìgbà tí ó ti wà ní Galili, tí wọn ń ṣe iranṣẹ fún un. Ọpọlọpọ àwọn obinrin mìíràn wà níbẹ̀ tí wọ́n bá a gòkè wá sí Jerusalẹmu. Ọjọ́ náà jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ tíí ṣe ọ̀sẹ̀ ku ọ̀la. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, Josẹfu ará Arimatia, ọlọ́lá kan ninu àwọn ìgbìmọ̀, wá. (Ó ń retí àkókò ìjọba Ọlọrun), ó bá fi ìgboyà tọ Pilatu lọ láti bèèrè òkú Jesu. *** Ṣugbọn ẹnu ya Pilatu pé Jesu ti yára kú! Ó pe ọ̀gágun, ó bèèrè bí Jesu ti kú tipẹ́. Nígbà tí ó gbọ́ ìròyìn ọ̀gágun náà, ó yọ̀ǹda òkú Jesu fún Josẹfu. Josẹfu bá ra aṣọ funfun kan, ó sọ òkú Jesu kalẹ̀, ó fi aṣọ náà wé e, ó tẹ́ ẹ sí ibojì tí wọ́n gbẹ́ sí inú àpáta, lẹ́yìn náà ó yí òkúta dí ẹnu ibojì náà. Maria Magidaleni ati Maria ìyá Josẹfu ń wo ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí. Lẹ́yìn tí Ọjọ́ Ìsinmi ti kọjá, Maria Magidaleni ati Maria ìyá Jakọbu ati Salomi ra òróró ìkunra, wọ́n fẹ́ lọ fi kun òkú Jesu. Ní àfẹ̀mọ́júmọ́ ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, wọ́n dé ibojì bí oòrùn ti ń yọ. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn ṣàròyé pé, “Ta ni yóo bá wa yí òkúta kúrò ní ẹnu ibojì?” Bí wọ́n ti gbé ojú sókè, wọ́n rí i pé ẹnìkan ti yí òkúta náà kúrò, bẹ́ẹ̀ ni òkúta ọ̀hún sì tóbi gan-an. *** Nígbà tí wọ́n wo inú ibojì, wọ́n rí ọdọmọkunrin kan tí ó jókòó ní apá ọ̀tún wọn, tí ó wọ aṣọ funfun. Wọ́n bá ta gìrì. Ṣugbọn ó wí fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù, ṣé Jesu ará Nasarẹti tí a kàn mọ́ agbelebu ni ẹ̀ ń wá? Ó ti jí dìde. Kò sí níhìn-ín. Ẹ wò ó! Ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí nìyí. Ṣugbọn ẹ lọ, ẹ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ati Peteru pé ó ti lọ ṣáájú yín sí Galili, níbẹ̀ ni ẹ óo gbé rí i, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fun yín.” Nígbà tí wọ́n jáde, aré ni wọ́n sá kúrò ní ibojì náà, nítorí ńṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, tí wọn ń dààmú. Wọn kò sọ ohunkohun fún ẹnikẹ́ni, nítorí ẹ̀rù ń bà wọ́n. [ Àwọn obinrin náà sọ ohun gbogbo tí a rán wọn fún Peteru ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní ṣókí. Lẹ́yìn èyí, Jesu fúnrarẹ̀ rán wọn lọ jákèjádò ayé láti kéde ìyìn rere ìgbàlà ayérayé, ìyìn rere tí ó ní ọ̀wọ̀, tí kò sì lè díbàjẹ́ lae.] [ (ÌPARÍ ÌYÌN RERE TÍ Ó GÙN) Jesu Fara han Maria Magidaleni (Mat 28:9-10; Joh 20:11-18) Nígbà tí Jesu jí dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, ó kọ́ fara han Maria Magidaleni, tí Jesu lé ẹ̀mí èṣù meje kúrò ninu rẹ̀ nígbà kan. Ó lọ sọ fún àwọn tí ó ti ń bá Jesu gbé níbi tí wọn ti ń ṣọ̀fọ̀, tí wọn ń sunkún. Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Jesu wà láàyè ati pé Maria ti rí i, wọn kò gbàgbọ́. Lẹ́yìn náà, ó fara han àwọn meji kan ninu wọn ní ọ̀nà mìíràn, bí wọ́n ti ń rìn lọ sí ìgbèríko kan. Wọ́n bá pada lọ ròyìn fún àwọn ìyókù. Sibẹ wọn kò gbàgbọ́. Lẹ́yìn náà ó fara han àwọn mọkanla bí wọ́n ti ń jẹun. Ó bá wọn wí fún aigbagbọ ati ọkàn líle wọn, nítorí wọn kò gba àwọn tí wọ́n rí i, tí wọ́n sọ pé ó ti jinde gbọ́. Ó bá sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí gbogbo ayé, kí ẹ máa waasu ìyìn rere fún gbogbo ẹ̀dá. Ẹni tí ó bá gbàgbọ́, tí ó bá ṣe ìrìbọmi, yóo ní ìgbàlà. Ẹni tí kò bá gbàgbọ́ yóo gba ìdálẹ́bi. Àwọn àmì tí yóo máa bá àwọn tí ó gbàgbọ́ lọ nìwọ̀nyí; wọn yóo máa lé ẹ̀mí burúkú jáde ní orúkọ mi; wọn yóo máa fi àwọn èdè titun sọ̀rọ̀; wọn yóo gbé ejò lọ́wọ́, wọn yóo mu òògùn olóró, ṣugbọn kò ní ṣe wọ́n léṣe; wọn yóo gbé ọwọ́ lé àwọn aláìsàn, ara wọn yóo sì dá.” Lẹ́yìn tí Jesu Oluwa ti bá wọn sọ̀rọ̀ tán, a gbé e lọ sí òkè ọ̀run, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun. Nígbà tí wọ́n túká lọ, wọ́n ń waasu ní ibi gbogbo, Oluwa ń bá wọ́n ṣiṣẹ́, ó ń fi ìdí ọ̀rọ̀ ìyìn rere múlẹ̀ nípa àwọn iṣẹ́ àmì tí ó ń bá wọn lọ.] Ọpọlọpọ eniyan ni wọ́n ti kọ ìròyìn lẹ́sẹẹsẹ, nípa ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ láàrin wa; àwọn tí nǹkan wọnyi ṣojú wọn, tí wọ́n sì sọ fún wa. Mo ti fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí ohun gbogbo fínnífínní. Èmi náà wá pinnu láti kọ ìwé sí ọ lẹ́sẹẹsẹ, ọlọ́lá jùlọ, Tiofilu, kí o lè mọ òtítọ́ àwọn nǹkan tí wọ́n kọ́ ọ. Ní àkókò Hẹrọdu, ọba Judia, alufaa kan wà tí ń jẹ́ Sakaraya, ní ìdílé Abiya. Orúkọ iyawo rẹ̀ ni Elisabẹti, láti inú ìdílé Aaroni. Àwọn mejeeji ń rìn déédé níwájú Ọlọrun, wọ́n ń pa gbogbo àwọn àṣẹ ati ìlànà Oluwa mọ́ láì kùnà. Ṣugbọn wọn kò ní ọmọ, nítorí pé Elisabẹti yàgàn. Àwọn mejeeji ni wọ́n sì ti di arúgbó. Nígbà tí ó yá, ó kan ìpín àwọn Sakaraya láti wá ṣe iṣẹ́ alufaa níwájú Ọlọrun ninu Tẹmpili. Gẹ́gẹ́ bí àṣà àwọn alufaa, Sakaraya ni ìbò mú láti sun turari ninu iyàrá Tẹmpili Oluwa. Gbogbo àwọn eniyan ń gbadura lóde ní àkókò tí ó ń sun turari. Angẹli Oluwa kan bá yọ sí i, ó dúró ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún pẹpẹ turari. Nígbà tí Sakaraya rí i, ó ta gìrì, ẹ̀rù bà á. Ṣugbọn angẹli náà sọ fún un pé, “Má bẹ̀rù, Sakaraya, nítorí pé adura rẹ ti gbà. Elisabẹti iyawo rẹ yóo bí ọmọkunrin kan fún ọ, o óo pe orúkọ rẹ̀ ní Johanu. Ayọ̀ yóo kún ọkàn rẹ. Ọpọlọpọ eniyan ni yóo bá ọ yọ̀ nígbà tí ẹ bá bí ọmọ náà. Ọmọ náà yóo jẹ́ ẹni ńlá níwájú Oluwa. Kò gbọdọ̀ mu ọtíkọ́tí, ìbáà jẹ́ líle tabi èyí tí kò le. Yóo kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ láti ìgbà tí ó bá tí wà ninu ìyá rẹ̀; ọpọlọpọ àwọn ọmọ Israẹli ni yóo sì yipada sí Oluwa Ọlọrun wọn. Òun ni yóo ṣáájú Oluwa pẹlu ẹ̀mí Elija ati agbára rẹ̀. Yóo mú kí àwọn baba wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu àwọn ọmọ wọn. Yóo yí àwọn alágídí ọkàn pada sí ọ̀nà rere. Yóo sọ àwọn eniyan di yíyẹ lọ́dọ̀ Oluwa.” Sakaraya bi angẹli náà pé, “Báwo ni n óo ti ṣe mọ̀? Nítorí pé mo ti di arúgbó; iyawo mi alára náà sì ti di àgbàlagbà.” Angẹli náà dá a lóhùn pé, “Geburẹli ni orúkọ mi, èmi ni mo máa ń dúró níwájú Ọlọrun. Ọlọrun ló rán mi láti bá ọ sọ̀rọ̀, ati láti sọ nǹkan ayọ̀ yìí fún ọ. Nítorí pé ìwọ kò gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́, o óo ya odi, o kò ní lè sọ̀rọ̀ títí ọjọ́ tí gbogbo nǹkan wọnyi yóo fi ṣẹlẹ̀. Gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ yìí yóo ṣẹ nígbà tí ó bá yá.” Àwọn eniyan ti ń retí Sakaraya. Ẹnu yà wọ́n pé ó pẹ́ ninu iyàrá Tẹmpili. Nígbà tí ó jáde, kò lè bá wọn sọ̀rọ̀. Wọ́n sì mọ̀ pé ó ti rí ìran ninu iyàrá Tẹmpili ni. Ó yadi, ọwọ́ ni ó fi ń ṣe àpèjúwe fún wọn. Nígbà tí ó parí àkókò tí yóo fi ṣiṣẹ́ alufaa ninu Tẹmpili, ó pada lọ sí ilé rẹ̀. Lẹ́yìn náà, Elisabẹti lóyún. Ó bá fi ara pamọ́ fún oṣù marun-un. Ó ní, “Oluwa ni ó ṣe èyí fún mi. Ó ti fi ojú àánú wò mí, ó sì ti mú ohun tí ó jẹ́ ẹ̀gàn fún mi lójú eniyan kúrò.” Ní oṣù kẹfa, Ọlọrun rán angẹli Geburẹli lọ sí ìlú kan ní Galili tí wọn ń pè ní Nasarẹti. Ọlọrun rán an lọ sí ọ̀dọ̀ wundia kan tí ó jẹ́ iyawo àfẹ́sọ́nà ọkunrin kan tí ń jẹ́ Josẹfu, ti ìdílé Dafidi. Wundia náà ń jẹ́ Maria. Angẹli náà wọlé tọ Maria lọ, ó kí i, ó ní “Alaafia ni fún ọ! Ìwọ ẹni tí Ọlọrun kọjú sí ṣe ní oore, Oluwa wà pẹlu rẹ.” Nígbà tí Maria gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ara rẹ̀ kò balẹ̀, ó ń rò lọ́kàn rẹ̀ pé, irú kíkí wo nìyí? Angẹli náà sọ fún un pé, “Má bẹ̀rù, Maria, nítorí o ti bá ojurere Ọlọrun pàdé. O óo lóyún, o óo sì bí ọmọkunrin kan, Jesu ni o óo pe orúkọ rẹ̀. Eniyan ńlá ni yóo jẹ́. Ọmọ Ọ̀gá Ògo ni a óo máa pè é. Oluwa Ọlọrun yóo fún un ní ìtẹ́ Dafidi, baba rẹ̀. Yóo jọba lórí ìdílé Jakọbu títí lae, ìjọba rẹ̀ kò ní lópin.” Maria bá bi angẹli náà pé, “Báwo ni yóo ti ṣe lè rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí n kò tíì mọ ọkunrin?” Angẹli náà dá a lóhùn pé, “Ẹ̀mí Mímọ́ yóo tọ̀ ọ́ wá, agbára Ọ̀gá Ògo yóo ṣíji bò ọ́. Nítorí náà Ọmọ Mímọ́ Ọlọrun ni a óo máa pe ọmọ tí ìwọ óo bí. Ati pé Elisabẹti, ìbátan rẹ náà ti lóyún ọmọkunrin kan ní ìgbà ogbó rẹ̀. Ẹni tí wọ́n ti ń pè ní àgàn rí sì ti di aboyún oṣù mẹfa. Nítorí kò sí ohun tí ó ṣòro fún Ọlọrun.” Maria bá dáhùn pé, “Iranṣẹ Oluwa ni mí. Kí ó rí fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.” Angẹli náà bá fi í sílẹ̀ lọ. Lẹ́yìn náà, Maria múra pẹlu ìwàǹwára, ó lọ sí ìlú Judia kan tí ó wà ní agbègbè orí òkè. Ó wọ inú ilé Sakaraya, ó bá kí Elisabẹti. Bí Elisabẹti ti gbọ́ ohùn Maria, bẹ́ẹ̀ ni ọlẹ̀ sọ ninu rẹ̀; Elisabẹti sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Ó kígbe sókè, ó ní, “Ibukun Ọlọrun wà lórí rẹ pupọ láàrin àwọn obinrin. Ibukun Ọlọrun sì wà lórí ọmọ inú rẹ. Mo ṣe ṣe oríire tó báyìí, tí ìyá Oluwa mi fi wá sọ́dọ̀ mi? Nítorí bí mo ti gbọ́ ohùn rẹ nígbà tí o kí mi, bẹ́ẹ̀ ni ọmọ inú mi sọ nítorí ó láyọ̀. Ayọ̀ ń bẹ fún ọ nítorí o gba ohun tí Oluwa ti sọ gbọ́, pé yóo ṣẹ.” Nígbà náà ni Maria sọ pé, “Ọkàn mi gbé Oluwa ga, ẹ̀mí mi yọ̀ sí Ọlọrun, Olùgbàlà mi, nítorí ó ti bojúwo ipò ìrẹ̀lẹ̀ iranṣẹbinrin rẹ̀. Wò ó! Láti ìgbà yìí lọ gbogbo ìran ni yóo máa pè mí ní olóríire. Nítorí Olodumare ti ṣe ohun ńlá fún mi, Mímọ́ ni orúkọ rẹ̀; àánú rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ fi agbára rẹ̀ hàn, ó tú àwọn tí ó gbéraga ninu ọkàn wọn ká. Ó yọ àwọn ìjòyè kúrò lórí oyè, ó gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ga. Ó fi oúnjẹ tí ó dára bọ́ àwọn tí ebi ń pa, ó mú àwọn ọlọ́rọ̀ jáde lọ́wọ́ òfo. Ó ran Israẹli ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ nígbà tí ó ranti àánú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí ó ti ṣe fún àwọn baba wa: fún Abrahamu ati fún ìdílé rẹ̀ títí lae.” Maria dúró lọ́dọ̀ Elisabẹti tó bíi oṣù mẹta, ó bá pada lọ sí ilé rẹ̀. Nígbà tí àkókò Elisabẹti tó tí yóo bí, ó bí ọmọkunrin kan. Àwọn aládùúgbò rẹ̀ ati àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ gbọ́ pé Oluwa ti ṣàánú pupọ fún un, wọ́n wá bá a yọ̀. Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹjọ, wọ́n wá láti kọ́ ọmọ náà ní ilà-abẹ́. Wọ́n fẹ́ sọ ọ́ ní Sakaraya, bí orúkọ baba rẹ̀. Ṣugbọn ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Rárá o! Johanu ni a óo máa pè é.” Wọ́n sọ fún un pé, “Kò sí ẹnìkan ninu àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ tí ó ń jẹ́ orúkọ yìí.” Wọ́n wá ṣe àpẹẹrẹ sí baba rẹ̀ pé báwo ni ó fẹ́ kí á máa pe ọmọ náà. Ó bá bèèrè fún nǹkan ìkọ̀wé, ó kọ ọ́ pé, “Johanu ni orúkọ rẹ̀.” Ẹnu ya gbogbo eniyan. Lẹsẹkẹsẹ ohùn Sakaraya bá là, okùn ahọ́n rẹ̀ tú, ó bá ń sọ̀rọ̀, ó ń yin Ọlọrun. Ẹ̀rù ńlá ba gbogbo àwọn aládùúgbò wọn. Ìròyìn tàn ká gbogbo agbègbè olókè Judia, wọ́n ń sọ ohun gbogbo tí ó ti ṣẹlẹ̀. Gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ń da ọ̀rọ̀ náà rò ninu ọkàn wọn, wọ́n ń sọ pé, “Irú ọmọ wo ni èyí yóo jẹ́?” Nítorí ọwọ́ Oluwa wà lára rẹ̀. Sakaraya, baba ọmọ náà, kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Ó bá sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé, Kí á yin Oluwa Ọlọrun Israẹli nítorí ó ti mú ìrànlọ́wọ́ wá fún àwọn eniyan rẹ̀, ó sì ti dá wọn nídè. Ó ti gbé Olùgbàlà dìde fún wa ní ìdílé Dafidi, iranṣẹ rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ láti ẹnu àwọn wolii rẹ̀ mímọ́, láti ọjọ́ pípẹ́; pé yóo gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa ati lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí ó kórìíra wa; pé yóo fi àánú bá àwọn baba wa lò, ati pé yóo ranti majẹmu rẹ̀ mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún Abrahamu baba wa, pé yóo gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, ati pé yóo fún wa ní anfaani láti máa sìn ín láì fòyà, pẹlu ọkàn kan ati pẹlu òdodo níwájú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé wa. “Ìwọ, ọmọ mi, wolii Ọ̀gá Ògo ni a óo máa pè ọ́, nítorí ìwọ ni yóo ṣáájú Oluwa láti palẹ̀ mọ́ dè é, láti fi ìmọ̀ ìgbàlà fún àwọn eniyan rẹ̀, nípa ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nítorí àánú Ọlọrun wa, nípa èyí tí oòrùn ìgbàlà fi ràn lé wa lórí láti òkè wá, láti tan ìmọ́lẹ̀ sí àwọn tí ó wà ní òkùnkùn ati àwọn tí ó jókòó níbi òjìji ikú, láti fi ẹsẹ̀ wa lé ọ̀nà alaafia.” Ọmọ náà ń dàgbà, ó sì ń lágbára sí i lára ati lẹ́mìí. Ilẹ̀ aṣálẹ̀ ni ó ń gbé títí di àkókò tí ó fara han àwọn eniyan Israẹli. Ní àkókò náà, àṣẹ kan jáde láti ọ̀dọ̀ Kesari Augustu pé kí gbogbo ayé lọ kọ orúkọ wọn sinu ìwé ìjọba. Èyí ni àkọsílẹ̀ ekinni tí wọ́n ṣe nígbà tí Kureniu jẹ́ gomina Siria. Gbogbo àwọn eniyan bá lọ kọ orúkọ wọn sílẹ̀, ẹnìkọ̀ọ̀kan lọ sí ìlú ara rẹ̀. Josẹfu náà gbéra láti Nasarẹti ìlú kan ní ilẹ̀ Galili, ó lọ sí ìlú Dafidi tí ó ń jẹ́ Bẹtilẹhẹmu, ní ilẹ̀ Judia, nítorí ẹbí Dafidi ni. Ó lọ kọ orúkọ sílẹ̀ pẹlu Maria iyawo àfẹ́sọ́nà rẹ̀, tí ó lóyún, tí ó sì fẹ́rẹ̀ bímọ. Ó wá yá nígbà tí wọ́n wà ní Bẹtilẹhẹmu, àkókò tó fún Maria láti bímọ. Ó bá bí àkọ́bí rẹ̀ ọmọkunrin, ó fi ọ̀já wé e, ó tẹ́ ẹ sí ibùjẹ ẹran, nítorí kò sí àyè fún wọn ninu ilé èrò. Ní àkókò náà, àwọn olùṣọ́-aguntan wà ní pápá, níbi tí wọn ń ṣọ́ aguntan wọn ní òru. Angẹli Oluwa kan bá yọ sí wọn, ògo Oluwa tan ìmọ́lẹ̀ yí wọn ká. Ẹ̀rù bà wọ́n gan-an. Ṣugbọn angẹli náà wí fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù mọ́, nítorí mo mú ìròyìn ayọ̀ ńlá fun yín wá, ayọ̀ tí yóo jẹ́ ti gbogbo eniyan. Nítorí a bí Olùgbàlà fun yín lónìí, ní ìlú Dafidi, tíí ṣe Oluwa ati Mesaya. Àmì tí ẹ óo fi mọ̀ ọ́n nìyí: ẹ óo rí ọmọ-ọwọ́ náà tí wọ́n fi ọ̀já wé, tí wọ́n tẹ́ sí ibùjẹ ẹran.” Lójijì ọpọlọpọ àwọn ogun ọ̀run yọ pẹlu angẹli náà, wọ́n ń yin Ọlọrun pé, “Ògo fún Ọlọrun lókè ọ̀run, alaafia ní ayé fún àwọn tí inú Ọlọrun dùn sí.” Lẹ́yìn tí àwọn angẹli náà ti pada kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ sí ọ̀run, àwọn olùṣọ́-aguntan ń sọ láàrin ara wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí Bẹtilẹhẹmu tààrà, kí á lè rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, tí Oluwa bùn wá gbọ́.” Wọ́n bá yára lọ. Wọ́n wá Maria kàn ati Josẹfu ati ọmọ-ọwọ́ náà tí a tẹ́ sí ibùjẹ ẹran. Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n sọ ohun gbogbo tí a ti sọ fún wọn nípa ọmọ náà. Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ohun tí àwọn olùṣọ́-aguntan náà sọ fún wọn. Ṣugbọn Maria ń ṣe akiyesi gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi, ó ń dà wọ́n rò ní ọkàn rẹ̀. Àwọn olùṣọ́-aguntan náà pada síbi iṣẹ́ wọn, wọ́n ń fi ògo ati ìyìn fún Ọlọrun fún gbogbo nǹkan tí wọ́n gbọ́, ati àwọn nǹkan tí wọ́n rí gẹ́gẹ́ bí angẹli náà ti sọ fún wọn. Nígbà tí ọjọ́ kẹjọ pé láti kọ ọmọ náà ní ilà-abẹ́, wọ́n sọ orúkọ rẹ̀ ní Jesu, gẹ́gẹ́ bí angẹli ti wí, kí ìyá rẹ̀ tó lóyún rẹ̀. Nígbà tí ó tó àkókò fún àwọn òbí rẹ̀ láti ṣe àṣà ìwẹ̀mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin Mose, wọ́n gbé ọmọ náà lọ sí Jerusalẹmu láti fi í fún Oluwa. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ ninu òfin Oluwa pé, “Gbogbo àkọ́bí lọkunrin ni a óo pè ní mímọ́ fún Oluwa.” Wọ́n tún lọ láti rú ẹbọ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà ninu òfin Oluwa: pẹlu àdàbà meji, tabi ọmọ ẹyẹlé meji. Ọkunrin kan wà ní Jerusalẹmu tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Simeoni. Ó jẹ́ olódodo eniyan ati olùfọkànsìn, ó ń retí àkókò tí Ọlọrun yóo tu Israẹli ninu. Ẹ̀mí Mímọ́ wà pẹlu rẹ̀. Ẹ̀mí Mímọ́ ti fihàn án pé kò ní tíì kú tí yóo fi rí Mesaya tí Oluwa ti ṣe ìlérí. Ẹ̀mí wá darí rẹ̀ sí Tẹmpili ní àkókò tí àwọn òbí ọmọ náà gbé e wá, láti ṣe gbogbo ètò tí ó yẹ gẹ́gẹ́ bí òfin. Ni Simeoni bá gbé ọmọ náà lọ́wọ́, ó yin Ọlọrun lógo, ó ní, “Nisinsinyii, Oluwa, dá ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ sílẹ̀ ní alaafia, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ. Nítorí ojú mi ti rí ìgbàlà rẹ, tí o ti pèsè níwájú gbogbo eniyan; ìmọ́lẹ̀ láti fi ọ̀nà han àwọn kèfèrí ati ògo fún Israẹli, eniyan rẹ.” Ẹnu ya baba ati ìyá Jesu nítorí ohun tí ó sọ nípa rẹ̀. Simeoni wá súre fún wọn. Ó sọ fún Maria ìyá rẹ̀ pé, “A gbé ọmọ yìí dìde fún ìṣubú ati ìdìde ọpọlọpọ ní Israẹli ati bí àmì tí àwọn eniyan yóo kọ̀. Nítorí yóo mú kí àṣírí èrò ọkàn ọpọlọpọ di ohun tí gbogbo eniyan yóo mọ̀. Ìbànújẹ́ yóo sì gún ọ ní ọkàn bí idà.” Wolii obinrin kan wà tí ń jẹ́ Ana, ọmọ Fanuẹli, ẹ̀yà Aṣeri. Arúgbó kùjọ́kùjọ́ ni. Ọdún meje péré ni ó ṣe ní ilé ọkọ, tí ọkọ rẹ̀ fi kú. Láti ìgbà náà ni ó ti di opó, ó sì tó ẹni ọdún mẹrinlelọgọrin ní àkókò yìí. Kì í fi ìgbà kan kúrò ninu Tẹmpili. Ó ń sìn pẹlu ààwẹ̀ ati ẹ̀bẹ̀ tọ̀sán-tòru. *** Ní àkókò náà gan-an ni ó dé, ó ń fi ìyìn fún Ọlọrun, ó ń sọ nípa ọmọ yìí fún gbogbo àwọn tí wọn ń retí àkókò ìdásílẹ̀ Jerusalẹmu. Lẹ́yìn tí wọ́n ti parí gbogbo nǹkan wọnyi tán gẹ́gẹ́ bí òfin Oluwa, wọ́n pada lọ sí Nasarẹti ìlú wọn ní ilẹ̀ Galili. Ọmọ náà ń dàgbà, ó ń lágbára, ó kún fún ọgbọ́n, ojurere Ọlọrun sì wà pẹlu rẹ̀. Àwọn òbí Jesu a máa lọ sí Àjọ̀dún Ìrékọjá ní Jerusalẹmu ní ọdọọdún. Nígbà tí Jesu di ọmọ ọdún mejila, wọ́n lọ sí àjọ yìí gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn. Nígbà tí àjọ̀dún parí, tí wọn ń pada lọ sí ilé, ọmọde náà, Jesu, dúró ní Jerusalẹmu, ṣugbọn àwọn òbí rẹ̀ kò fura. Wọ́n ṣebí ó wà láàrin ọ̀pọ̀ eniyan tí ń kọ́wọ̀ọ́ rìn ni. Lẹ́yìn tí wọ́n rin ìrìn ọjọ́ kan, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá a kiri láàrin àwọn mọ̀lẹ́bí ati àwọn ojúlùmọ̀ wọn. Nígbà tí wọn kò rí i, wọ́n pada lọ sí Jerusalẹmu, wọ́n ń wá a. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹta, wọ́n rí i ninu Tẹmpili, ó jókòó láàrin àwọn olùkọ́ni, ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn, òun náà sì ń bi wọ́n ní ìbéèrè. Ẹnu ya gbogbo àwọn tí wọn gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nítorí òye rẹ̀ ati nítorí bí ó ṣe ń dáhùn àwọn ìbéèrè tí wọn ń bi í. Nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ rí i, ẹnu yà wọ́n. Ìyá rẹ̀ bá bi í pé, “Ọmọ, kí ló dé tí o fi ṣe wá báyìí? Èmi ati baba rẹ dààmú pupọ nígbà tí à ń wá ọ.” Ó dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń wá mi kiri? Ẹ kò mọ̀ pé dandan ni fún mi kí n wà ninu ilé Baba mi?” Gbolohun tí ó sọ fún wọn yìí kò sì yé wọn. Ó bá bá wọn lọ sí Nasarẹti, ó sì ń gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu. Ìyá rẹ̀ pa gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi mọ́ ní ọkàn rẹ̀. Bí Jesu ti ń dàgbà, bẹ́ẹ̀ ni ọgbọ́n rẹ̀ ń pọ̀ sí i, ó sì ń bá ojurere Ọlọrun ati ti àwọn eniyan pàdé. Ní ọdún kẹẹdogun tí Ọba Tiberiu ti wà lórí oyè, nígbà tí Pọntiu Pilatu jẹ́ gomina Judia, tí Hẹrọdu jẹ́ baálẹ̀ Galili, tí Filipi arakunrin rẹ̀ jẹ́ baálẹ̀ Ituria ati ti agbègbè Tirakoniti, Lusaniu jẹ́ baálẹ̀ Abilene; Anasi ati Kayafa sì jẹ́ olórí alufaa. Johanu ọmọ Sakaraya gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní aṣálẹ̀ tí ó wà. Ó bá ń kiri gbogbo ìgbèríko odò Jọdani, ó ń waasu pé kí àwọn eniyan ronupiwada, kí wọ́n ṣe ìrìbọmi, kí Ọlọrun lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wọ́n. Èyí rí bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ninu ìwé ọ̀rọ̀ wolii Aisaya pé, “Ohùn ẹni tí ń kígbe ní aṣálẹ̀ pé, ‘Ẹ la ọ̀nà fún Oluwa, ẹ ṣe ojú ọ̀nà tí ó tọ́ fún un láti rìn! Gbogbo ọ̀gbun ni yóo jẹ́ dídí gbogbo òkè gíga ati òkè kéékèèké ni yóo jẹ́ rírẹ̀ sílẹ̀. A óo tọ́ ibi tí ó bá ṣe kọ́rọ-kọ̀rọ, a óo sì sọ ọ̀nà tí kò bá dán tẹ́lẹ̀ di dídán Gbogbo eniyan ni yóo rí ìgbàlà Ọlọrun.’ ” Johanu ń sọ fún àwọn eniyan tí ó jáde lọ ṣe ìrìbọmi lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fun yín láti sá fún ibinu tí ń bọ̀? Ẹ fihàn ninu ìwà yín pé ẹ ti ronupiwada. Ẹ má bẹ̀rẹ̀ láti máa rò ninu ara yín pé, ‘A ní Abrahamu ní baba.’ Nítorí mò ń sọ fun yín pé Ọlọrun lè gbé ọmọ dìde fún Abrahamu láti inú òkúta wọnyi. A sì ti fi àáké lé gbòǹgbò igi báyìí. Nítorí náà, igikígi tí kò bá máa so èso rere ni a óo gé lulẹ̀, tí a óo sì fi dáná.” Àwọn eniyan wá bi í pé, “Kí ni kí a wá ṣe?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹni tí ó bá ní dàńṣíkí meji, kí ó fún ẹni tí kò ní lọ́kan. Ẹni tí ó bá ní oúnjẹ níláti ṣe bákan náà.” Àwọn agbowó-odè náà wá láti ṣe ìrìbọmi. Wọ́n bi í pé, “Olùkọ́ni, kí ni kí a ṣe?” Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe gbà ju iye tí ó tọ́ lọ.” Àwọn ọmọ-ogun náà ń bi í pé, “Àwa náà ńkọ́, kí ni kí a ṣe?” Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe dẹ́rù ba ẹnikẹ́ni láti lọ́ wọn lọ́wọ́ gbà, Ẹ má ṣe fi ẹ̀sùn èké kan ẹnikẹ́ni. Ẹ jẹ́ kí owó oṣù yín to yín.” Àwọn eniyan ń retí, gbogbo wọn ń rò ninu ọkàn wọn bí Johanu bá ni Mesaya. Johanu sọ fún gbogbo eniyan pé, “Omi ni èmi fi ń ṣe ìwẹ̀mọ́ fun yín, ṣugbọn ẹni tí ó jù mí lọ ń bọ̀. Èmi kò tó ẹni tíí tú okùn bàtà rẹ̀. Ẹ̀mí Mímọ́ ati iná ni yóo fi wẹ̀ yín mọ́. Àtẹ ìfẹ́kà ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀ tí yóo fi fẹ́ ọkà inú oko rẹ̀; yóo kó ọkà rẹ̀ sinu abà, yóo sì sun fùlùfúlù ninu iná àjóòkú.” Ní ọ̀nà yìí ati ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà mìíràn, Johanu ń gba àwọn eniyan níyànjú, ó sì ń sọ̀rọ̀ ìyìn rere fún wọn. Ní àkókò kan, Johanu bá Hẹrọdu baálẹ̀ wí nítorí ọ̀ràn Hẹrọdiasi, iyawo Filipi, arakunrin rẹ̀, tí Hẹrọdu gbà. Ó tún bá a wí fún gbogbo nǹkan burúkú mìíràn tí ó ṣe. Hẹrọdu wá tún fi ti Johanu tí ó sọ sẹ́wọ̀n kún gbogbo ìwà burúkú rẹ̀. Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan ń ṣe ìrìbọmi, Jesu náà ṣe ìrìbọmi. Lẹ́yìn náà, bí ó ti ń gbadura, ọ̀run ṣí sílẹ̀. Ẹ̀mí Mímọ́ fò wálẹ̀ bí àdàbà ó bà lé e lórí. Ohùn kan wá fọ̀ láti ọ̀run pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ Ọmọ mi; inú mi dùn sí ọ gidigidi.” Jesu tó ẹni ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀. Ọmọ Josẹfu ni àwọn eniyan mọ̀ ọ́n sí. Josẹfu jẹ́ ọmọ Eli, ọmọ Matati, ọmọ Lefi, ọmọ Meliki, ọmọ Janai, ọmọ Josẹfu, ọmọ Matatiya, ọmọ Amosi, ọmọ Nahumu, ọmọ Esili, ọmọ Nagai, ọmọ Maati, ọmọ Matatiya, ọmọ Semehin, ọmọ Joseki, ọmọ Joda, ọmọ Johana, ọmọ Resa, ọmọ Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, ọmọ Neri, ọmọ Meliki, ọmọ Adi, ọmọ Kosamu, ọmọ Elimadamu, ọmọ Eri, ọmọ Joṣua ọmọ Elieseri, ọmọ Jorimu, ọmọ Matati, ọmọ Lefi, ọmọ Simeoni, ọmọ Juda, ọmọ Josẹfu, ọmọ Jonamu, ọmọ Eliakimu, ọmọ Melea, ọmọ Mena, ọmọ Matati, ọmọ Natani, ọmọ Dafidi, ọmọ Jese, ọmọ Obedi, ọmọ Boasi, ọmọ Salimoni, ọmọ Naṣoni, ọmọ Aminadabu, ọmọ Adimini, ọmọ Arini, ọmọ Hesironi, ọmọ Pẹrẹsi, ọmọ Juda, ọmọ Jakọbu, ọmọ Isaaki, ọmọ Abrahamu, ọmọ Tẹra, ọmọ Nahori, ọmọ Serugi, ọmọ Reu, ọmọ Pelegi, ọmọ Eberi, ọmọ Sela, ọmọ Kainani, ọmọ Afasadi, ọmọ Ṣemu, ọmọ Noa, ọmọ Lamẹki, ọmọ Metusela, ọmọ Enọku, ọmọ Jaredi, ọmọ Mahalaleli, ọmọ Kenani, ọmọ Enọṣi, ọmọ Seti, ọmọ Adamu, ọmọ Ọlọrun. Jesu pada láti odò Jọdani, ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ̀mí bá darí rẹ̀ lọ sí aṣálẹ̀. Ogoji ọjọ́ ni èṣù fi dán an wò. Kò jẹ ohunkohun ní gbogbo àkókò náà. Lẹ́yìn náà, ebi wá ń pa á. Èṣù sọ fún un pé, “Bí ó bá jẹ́ pé Ọmọ Ọlọrun ni ọ́ nítòótọ́, sọ fún òkúta yìí pé kí ó di àkàrà.” Jesu dá a lóhùn pé, “Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Kì í ṣe oúnjẹ nìkan ni yóo mú kí eniyan wà láàyè.’ ” Èṣù bá mú un lọ sí orí òkè kan, ó fi gbogbo ìjọba ayé hàn án ní ìṣẹ́jú kan. Ó sọ fún Jesu pé, “Ìwọ ni n óo fún ní gbogbo àṣẹ yìí ati ògo rẹ̀, nítorí èmi ni a ti fi wọ́n lé lọ́wọ́, ẹni tí ó bá sì wù mí ni mo lè fún. Tí o bá júbà mi, tìrẹ ni gbogbo rẹ̀ yóo dà.” Jesu dá a lóhùn pé, “Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Oluwa Ọlọrun rẹ ni kí o máa júbà, òun nìkan ni kí o sì máa sìn!’ ” Èṣù tún mú un lọ sí Jerusalẹmu. Ó gbé e ka téńté òrùlé Tẹmpili. Ó ní, “Bí ó bá jẹ́ pé Ọmọ Ọlọrun ni ọ́ nítòótọ́, bẹ́ sílẹ̀ láti ìhín. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Yóo pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀ nítorí rẹ pé kí wọn pa ọ́ mọ́.’ Ati pé, ‘Kí wọn tẹ́wọ́ gbà ọ́ kí o má baà fi ẹsẹ̀ gbún òkúta.’ ” Jesu dá a lóhùn pé, “A ti sọ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Oluwa Ọlọrun rẹ wò.’ ” Nígbà tí Satani parí gbogbo ìdánwò yìí, ó fi Jesu sílẹ̀ títí di àkókò tí ó bá tún wọ̀. Jesu pada sí Galili pẹlu agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Òkìkí rẹ̀ kàn ká gbogbo ìgbèríko. Ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu àwọn ilé ìpàdé wọn. Gbogbo eniyan sì ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní rere. Ó wá dé Nasarẹti, ìlú tí wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, nígbà tí ó di ọjọ́ ìsinmi, ó lọ sí ilé ìpàdé. Ó bá dìde láti ka Ìwé Mímọ́. Wọ́n fún un ní ìwé wolii Aisaya. Nígbà tí ó ṣí i, ó rí ibi tí a gbé kọ ọ́ pé, “Ẹ̀mí Oluwa wà pẹlu mi nítorí ó ti fi òróró yàn mí láti waasu ìyìn rere fún àwọn talaka. Ó rán mi láti waasu ìtúsílẹ̀ fún àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèkùn, ati láti mú kí àwọn afọ́jú ríran; láti jẹ́ kí àwọn tí a ni lára lọ ní alaafia, ati láti waasu ọdún tí Oluwa yóo gba àwọn eniyan rẹ̀ là.” Ó bá pa ìwé náà dé, ó fi í fún olùtọ́jú ilé ìpàdé, ó bá jókòó. Gbogbo àwọn eniyan tí ó wà ninu ilé ìpàdé tẹjú mọ́ ọn; ó bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún wọn pé, “Lónìí ni àkọsílẹ̀ yìí ṣẹ ní ojú yín.” Gbogbo wọn ni wọ́n gbà fún un, ẹnu sì yà wọ́n fún ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ tí ó ń sọ jáde, wọ́n wá ń sọ pé, “Àbí ọmọ Josẹfu kọ́ nìyí ni?” Ó sọ fún wọn pé, “Ní òtítọ́ ẹ lè pa òwe yìí fún mi pé, ‘Oníṣègùn, wo ara rẹ sàn! Ohun gbogbo tí a gbọ́ pé o ṣe ní Kapanaumu, ṣe wọ́n níhìn-ín, ní ìlú baba rẹ.’ ” Ó tún fi kún un pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé kò sí wolii kan tíí ní iyì ní ìlú baba rẹ̀. “Òtítọ́ ni mo sọ fun yín pé opó pọ̀ ní Israẹli ní àkókò Elija, nígbà tí kò fi sí òjò fún ọdún mẹta ati oṣù mẹfa, tí ìyàn fi mú níbi gbogbo. A kò rán Elija sí ọ̀kankan ninu wọn. Ọ̀dọ̀ ẹni tí a rán an sí ni opó kan ní Sarefati ní agbègbè Sidoni. Àwọn adẹ́tẹ̀ pọ̀ ní Israẹli ní àkókò wolii Eliṣa. Kò sí ọ̀kan ninu wọn tí a wòsàn, àfi Naamani ará Siria.” Nígbà tí àwọn tí ó wà ninu ilé ìpàdé gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, inú bí gbogbo wọn. Wọ́n dìde, wọ́n tì í sẹ́yìn odi ìlú, wọ́n sì fà á lọ sí ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ibi tí ìlú wọn wà, wọ́n fẹ́ taari rẹ̀ ní ogedengbe. Ṣugbọn ó la ààrin wọn kọjá, ó bá tirẹ̀ lọ. Jesu bá lọ sí Kapanaumu, ìlú kan ní ilẹ̀ Galili. Ó ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ ní Ọjọ́ Ìsinmi. Ẹnu yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ̀, nítorí pẹlu àṣẹ ni ó fi ń sọ̀rọ̀. Ọkunrin kan wà ninu ilé ìpàdé tí ó ní ẹ̀mí èṣù. Ó bá kígbe tòò, ó ní, “Háà! Kí ni ó pa tàwa-tìrẹ pọ̀, Jesu ará Nasarẹti? Ṣé o wá pa wá run ni? Mo mọ ẹni tí o jẹ́. Ẹni Mímọ́ ti Ọlọrun ni ọ́.” Jesu bá bá a wí, ó ní, “Pa ẹnu mọ́, kí o jáde kúrò ninu ọkunrin yìí!” Ẹ̀mí èṣù náà bá gbé ọkunrin náà ṣánlẹ̀ lójú gbogbo wọn, ó bá jáde kúrò lára rẹ̀, láì pa á lára. Ẹnu ya gbogbo eniyan. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Irú ọ̀rọ̀ wo ni èyí? Nítorí pẹlu àṣẹ ati agbára ni ó fi bá àwọn ẹ̀mí èṣù wí, wọ́n sì ń jáde!” Òkìkí Jesu sì kàn ká gbogbo ìgbèríko ibẹ̀. Nígbà tí Jesu dìde kúrò ní ilé ìpàdé, ó wọ ilé Simoni lọ. Ìyá iyawo Simoni ń ṣàìsàn akọ ibà. Wọ́n bá sọ fún Jesu. Ó bá lọ dúró lẹ́bàá ibùsùn ìyá náà, ó bá ibà náà wí, ibà sì fi ìyá náà sílẹ̀. Lẹsẹkẹsẹ ó dìde, ó bá tọ́jú oúnjẹ fún wọn. Nígbà tí oòrùn wọ̀, gbogbo àwọn tí wọ́n ní oríṣìíríṣìí àrùn ni wọ́n mú wá sọ́dọ̀ Jesu. Ó bá gbé ọwọ́ lé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, ó wò wọ́n sàn. Àwọn ẹ̀mí èṣù jáde kúrò ninu ọpọlọpọ eniyan, wọ́n ń kígbe pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọrun.” Jesu ń bá wọn wí, kò jẹ́ kí wọ́n sọ̀rọ̀, nítorí wọ́n mọ̀ pé Jesu ni Mesaya. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, Jesu jáde lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú níbi tí kò sí ẹnìkankan. Àwọn eniyan ń wá a kiri. Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n fẹ́ dá a dúró kí ó má kúrò lọ́dọ̀ wọn. Ṣugbọn ó sọ fún wọn pé, “Dandan ni fún mi láti waasu ìyìn rere ìjọba ọ̀run ní àwọn ìlú mìíràn, nítorí ohun tí Ọlọrun rán mi wá ṣe nìyí.” Ni ó bá ń waasu ní gbogbo àwọn ilé ìpàdé ní Judia. Ní àkókò kan, bí Jesu ti dúró létí òkun Genesarẹti, ọ̀pọ̀ eniyan péjọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ó rí àwọn ọkọ̀ meji létí òkun. Àwọn apẹja ti kúrò ninu àwọn ọkọ̀ yìí, wọ́n ń fọ àwọ̀n wọn. Jesu bá wọ inú ọ̀kan ninu àwọn ọkọ̀ náà tí ó jẹ́ ti Simoni, ó ní kí wọ́n tù ú kúrò létí òkun díẹ̀. Ni ó bá jókòó ninu ọkọ̀, ó ń kọ́ àwọn eniyan. Nígbà tí ó parí ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, ó sọ fún Simoni pé, “Tu ọkọ̀ lọ sí ibú, kí o da àwọ̀n sí omi kí ó lè pa ẹja.” Simoni dáhùn pé, “Alàgbà, gbogbo òru ni a fi ṣiṣẹ́ láì rí ohunkohun pa, ṣugbọn nítorí ọ̀rọ̀ rẹ, n óo da àwọ̀n sí omi.” Nígbà tí ó dà á sinu omi, ẹja tí ó kó pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí àwọ̀n fẹ́ ya. Wọ́n bá ṣe àmì sí àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tí ó wà ninu ọkọ̀ keji pé kí wọ́n wá ràn wọ́n lọ́wọ́. Nígbà tí wọ́n dé, wọ́n da ẹja kún inú ọkọ̀ mejeeji, tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi fẹ́ rì. Nígbà tí Simoni Peteru rí i, ó kúnlẹ̀ níwájú Jesu, ó ní “Kúrò lọ́dọ̀ mi, nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí, Oluwa.” Nítorí ẹnu yà á ati gbogbo àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ fún ọpọlọpọ ẹja tí wọ́n rí pa. Ẹnu ya Jakọbu náà ati Johanu, àwọn ọmọ Sebede, tí wọ́n jẹ́ ẹlẹgbẹ́ Simoni. Jesu wá sọ fún Peteru pé, “Má bẹ̀rù. Láti ìgbà yìí lọ eniyan ni ìwọ yóo máa mú wá.” Nígbà tí wọ́n tu ọkọ̀ dé èbúté, wọ́n fi ohun gbogbo sílẹ̀, wọ́n ń tẹ̀lé e. Ní àkókò kan nígbà tí Jesu wà ninu ìlú kan, ọkunrin kan tí ẹ̀tẹ̀ bò ní gbogbo ara rí i. Ó bá wá dojúbolẹ̀, ó ń bẹ̀ ẹ́ pé, “Alàgbà, bí o bá fẹ́, o lè sọ ara mi di mímọ́.” Jesu bá na ọwọ́, ó fi kàn án, ó ní, “Mo fẹ́ kí ara rẹ di mímọ́.” Lẹsẹkẹsẹ àrùn ẹ̀tẹ̀ náà fi í sílẹ̀. Jesu bá kìlọ̀ fún un pé, “Má ṣe sọ fún ẹnikẹ́ni, ṣugbọn lọ fi ara rẹ han alufaa, kí o ṣe ìrúbọ fún ìsọdi-mímọ́ rẹ, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ. Èyí yóo jẹ́ ẹ̀rí fún wọn pé ara rẹ ti dá.” Ṣugbọn ńṣe ni ìròyìn rẹ̀ túbọ̀ ń tàn kálẹ̀. Ọ̀pọ̀ eniyan wá ń péjọ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ati kí ó lè wò wọ́n sàn kúrò ninu àìlera wọn. Ṣugbọn aṣálẹ̀ ni ó máa ń lọ láti dá gbadura. Ní ọjọ́ kan bí Jesu ti ń kọ́ àwọn eniyan, àwọn Farisi ati àwọn amòfin jókòó níbẹ̀. Wọ́n wá láti gbogbo ìletò Galili ati ti Judia ati láti Jerusalẹmu. Agbára Oluwa wà pẹlu Jesu láti fi ṣe ìwòsàn. Àwọn ẹnìkan gbé ọkunrin arọ kan wá tí ó dùbúlẹ̀ sórí ibùsùn rẹ̀. Wọ́n ń wá ọ̀nà láti gbé e dé iwájú Jesu. Nígbà tí wọn kò rí ọ̀nà gbé e dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ nítorí ọ̀pọ̀ eniyan, wọ́n gbé e gun orí òrùlé. Wọ́n bá dá òrùlé lu kí wọ́n fi lè gbé arọ náà pẹlu ibùsùn rẹ̀ sí ààrin àwọn eniyan níwájú Jesu. Nígbà tí Jesu rí igbagbọ wọn, ó ní, “Arakunrin, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.” Àwọn amòfin ati àwọn Farisi bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn sọ pé, “Ta ni eléyìí tí ó ń sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun báyìí? Ta ni lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan lẹ́yìn Ọlọrun nìkan ṣoṣo?” Jesu ti mọ ohun tí wọ́n ń bá ara wọn sọ, ó bá dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń ro irú èrò báyìí ní ọkàn yín? Èwo ni ó rọrùn jù, láti sọ pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́ ni,’ tabi láti sọ pé, ‘Dìde kí o máa rìn’? Ṣugbọn kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ-Eniyan ní àṣẹ ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan ni,” ó bá sọ fún arọ náà pé, “Mo sọ fún ọ, dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o máa lọ sí ilé rẹ.” Lẹsẹkẹsẹ ó dìde lójú gbogbo wọn, ó gbé ibùsùn rẹ̀, ó lọ sí ilé rẹ̀, ó ń yin Ọlọrun lógo. Ẹnu ya gbogbo àwọn eniyan. Wọ́n ń yin Ọlọrun lógo. Ẹ̀rù bà wọ́n pupọ. Wọ́n ń sọ pé, “Ìròyìn kò tó àfojúbà ni ohun tí a rí lónìí!” Lẹ́yìn èyí Jesu jáde lọ. Ó rí agbowó-odè kan tí ó ń jẹ́ Lefi tí ó jókòó níbi tí ó ti ń gba owó-odè. Jesu sọ fún un pé, “Máa tẹ̀lé mi.” Ó bá fi ohun gbogbo sílẹ̀, ó dìde, ó ń tẹ̀lé e. Lefi bá se àsè ńlá fún Jesu ninu ilé rẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn agbowó-odè wà níbẹ̀ pẹlu àwọn ẹlòmíràn, tí wọn ń bá wọn jẹun. Àwọn Farisi ati àwọn amòfin tí wọ́n wà ninu ẹgbẹ́ wọn wá ń kùn sí Jesu. Wọ́n bi í pé, “Kí ló dé tí o fi ń bá àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹ, tí ò ń bá wọn mu?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àwọn tí ara wọn le kò nílò oníṣègùn, bíkòṣe àwọn tí ara wọn kò dá. Èmi kò wá láti pe àwọn olódodo. Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mo wá pè sí ìrònúpìwàdà.” Àwọn kan sọ fún un pé, “Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ń gbààwẹ̀ nígbà pupọ, wọn a sì máa gbadura. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn Farisi. Ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ ń jẹ, wọ́n ń mu ní tiwọn ni.” Jesu dá wọn lóhùn pé, “àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ iyawo kò lè máa gbààwẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ iyawo bá wà pẹlu wọn. Ṣugbọn ọjọ́ ń bọ̀ tí a óo mú ọkọ iyawo kúrò lọ́dọ̀ wọn. Wọn óo máa gbààwẹ̀ nígbà náà.” Jesu wá pa òwe kan fún wọn pé, “Kò sí ẹni tí ó jẹ́ ya lára ẹ̀wù titun kí ó fi lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù. Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó ti ba ẹ̀wù titun jẹ́, aṣọ titun tí ó sì fi lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù kò bá ara wọn mu. Kò sí ẹni tíí fi ọtí titun sinu ògbólógbòó àpò awọ. Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ọtí titun yóo bẹ́ àpò, ọtí yóo tú dànù, àpò yóo sì tún bàjẹ́. Ṣugbọn ninu àpò awọ titun ni wọ́n ń fi ọtí titun sí. Kò sí ẹni tí ó bá ti mu ọtí tí ó mú, tíí fẹ́ mu ọtí àṣẹ̀ṣẹ̀pọn. Nítorí yóo sọ pé, ‘Ọtí tí ó mú ni ó dára.’ ” Ní Ọjọ́ Ìsinmi kan, bí Jesu ti ń la oko ọkà kan kọjá, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí já ọkà, wọ́n ń fi ọwọ́ ra á, wọ́n bá ń jẹ ẹ́. Àwọn kan ninu àwọn Farisi sọ pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe ohun tí kò tọ́ ní Ọjọ́ Ìsinmi?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ṣé ẹ kò ì tíì ka ohun tí Dafidi ṣe nígbà tí ebi ń pa òun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀? Bí ó ti wọ ilé Ọlọrun lọ, tí ó mú burẹdi tí ó wà lórí tabili níwájú Oluwa, tí ó jẹ ẹ́, tí ó tún fún àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́ àfi àwọn alufaa nìkan?” Jesu bá sọ fún wọn pé, “Ọmọ-Eniyan ni Oluwa Ọjọ́ Ìsinmi.” Nígbà tí ó di Ọjọ́ Ìsinmi mìíràn, Jesu wọ inú ilé ìpàdé lọ, ó ń kọ́ àwọn eniyan. Ọkunrin kan wà níbẹ̀ tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ rọ. Àwọn amòfin ati àwọn Farisi ń ṣọ́ Jesu bí yóo ṣe ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi kí wọ́n lè rí ẹ̀sùn fi kàn án. Ṣugbọn ó ti mọ ohun tí wọn ń rò ní ọkàn wọn. Ó sọ fún ọkunrin náà tí ọwọ́ rẹ̀ rọ pé, “Dìde kí o dúró ní ààrin.” Ọkunrin náà bá dìde dúró. Jesu wá sọ fún wọn pé, “Mo bi yín, èwo ni ó bá òfin mu, láti ṣe nǹkan rere tabi nǹkan burúkú ní Ọjọ́ Ìsinmi? Láti gba ẹ̀mí là, tabi láti pa á run?” Ó wá wo gbogbo wọn yíká, ó sọ fún ọkunrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ.” Ó ṣe bẹ́ẹ̀. Ọwọ́ rẹ̀ bá bọ́ sípò. Inú wọn ru sókè, wọ́n wá ń bá ara wọn jíròrò nípa ohun tí wọn ìbá ṣe sí Jesu. Ní ọjọ́ kan, Jesu lọ sí orí òkè, ó lọ gbadura. Gbogbo òru ni ó fi gbadura sí Ọlọrun. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó yan àwọn mejila ninu wọn, tí ó pè ní aposteli. Àwọn ni Simoni tí ó sọ ní Peteru ati Anderu arakunrin rẹ̀, Jakọbu ati Johanu, Filipi ati Batolomiu, Matiu ati Tomasi, Jakọbu ọmọ Alfeu ati Simoni tí ó tún ń jẹ́ Seloti, Judasi ọmọ Jakọbu ati Judasi Iskariotu, ẹni tí ó di ọ̀dàlẹ̀. Nígbà tí Jesu sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè pẹlu wọn, ó dúró ní ibi tí ilẹ̀ gbé tẹ́jú. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ati ọ̀pọ̀ àwọn eniyan láti gbogbo Judia ati Jerusalẹmu ati Tire ati Sidoni, ní agbègbè ẹ̀bá òkun. Wọ́n wá gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ati pé kí ó lè wò wọ́n sàn kúrò ninu àìsàn wọn. Ó tún ń wo àwọn tí ẹ̀mí Èṣù ń dà láàmú sàn. Gbogbo àwọn eniyan ni ó ń wá a, kí wọ́n lè fi ọwọ́ kàn án nítorí agbára ń ti ara rẹ̀ jáde. Ó bá wo gbogbo wọn sàn. Ó bá gbé ojú sókè sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ fún wọn pé, “Ayọ̀ ń bẹ fún ẹ̀yin talaka, nítorí tiyín ni ìjọba Ọlọrun. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹ̀yin tí ebi ń pa nisinsinyii, nítorí ẹ óo yó. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sunkún nisinsinyii, nítorí ẹ óo rẹ́rìn-ín. “Ayọ̀ ń bẹ fun yín nígbà tí àwọn eniyan bá kórìíra yín, tí wọ́n bá le yín ní ìlú bí arúfin, tí wọ́n bá kẹ́gàn yín, tí wọ́n bá fi orúkọ yín pe ibi, nítorí Ọmọ-Eniyan. Ẹ máa yọ̀ ní ọjọ́ náà, kí ẹ sì máa jó, nítorí èrè pọ̀ fun yín ní ọ̀run. Irú nǹkan báwọ̀nyí ni àwọn baba wọn ṣe sí àwọn wolii. “Ṣugbọn ẹ̀yin ọlọ́rọ̀ gbé, nítorí ẹ ti jẹ ìgbádùn tiyín tán! Ẹ̀yin tí ẹ yó nisinsinyii, ẹ gbé, nítorí ebi ń bọ̀ wá pa yín. Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń yọ̀ nisinsinyii, ẹ gbé, nítorí ọ̀fọ̀ óo ṣẹ̀ yín, ẹ óo sì sunkún. “Nígbà tí gbogbo eniyan bá ń ròyìn yín ní rere, ẹ gbé, nítorí bẹ́ẹ̀ ni àwọn baba wọn ṣe sí àwọn èké wolii. “Ṣugbọn fún ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, mo sọ fun yín pé: ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín: ẹ máa ṣoore fún àwọn tí ó kórìíra yín. Ẹ máa súre fún àwọn tí ó ń gbe yín ṣépè. Ẹ máa gbadura fún àwọn tí wọn ń ṣe àìdára si yín. Bí ẹnìkan bá gba yín létí, ẹ yí ẹ̀gbẹ́ keji sí i. Ẹni tí ó bá gba agbádá yín, ẹ má ṣe du dàńṣíkí yín mọ́ ọn lọ́wọ́. Bí ẹnikẹ́ni bá tọrọ nǹkan lọ́wọ́ yín, ẹ fún un. Bí ẹnìkan bá mú nǹkan yín, ẹ má bèèrè rẹ̀ pada. Bí ẹ bá ti fẹ́ kí eniyan máa ṣe si yín, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ máa ṣe sí wọn. “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn tí ó fẹ́ràn yín nìkan ni ẹ fẹ́ràn kí ni fáàrí yín? Nítorí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá fẹ́ràn àwọn tí ó bá fẹ́ràn wọn. Bí ẹ bá ń ṣe rere sí àwọn tí wọn ń ṣe rere si yín, kí ni fáàrí yín? Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá ń ṣe bẹ́ẹ̀. Bí ẹ bá yá eniyan lówó tí ó jẹ́ ẹni tí ẹ nírètí pé yóo san án pada, kí ni fáàrí yín. Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá ń yá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ẹgbẹ́ wọn lówó kí wọn lè rí i gbà pada ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Ṣugbọn ẹ máa fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín; ẹ ṣoore. Ẹ máa yá eniyan lówó láì ní ìrètí láti gbà á pada. Èrè yín yóo pọ̀, ẹ óo wá jẹ́ ọmọ Ọ̀gá Ògo nítorí ó ń ṣoore fún àwọn aláìmoore ati àwọn eniyan burúkú. Ẹ jẹ́ aláàánú gẹ́gẹ́ bí Baba yín ti jẹ́ aláàánú. “Ẹ má ṣe dá eniyan lẹ́jọ́, kí Ọlọrun má baà dá ẹ̀yin náà lẹ́jọ́. Ẹ má ṣe dá eniyan lẹ́bi. Ẹ máa dáríjì eniyan, Ọlọrun yóo sì dáríjì yín. Ẹ máa fún eniyan lẹ́bùn, Ọlọrun yóo sì fun yín ní ẹ̀bùn. Òṣùnwọ̀n rere, tí a kì tí ó kún, tí a mì dáradára, tí ó kún tí ó ń ṣàn sílẹ̀ ni a óo fi wọ̀n ọ́n le yín lọ́wọ́. Nítorí òṣùnwọ̀n tí ẹ bá lò fún ẹlòmíràn ni a óo lò fun yín.” Jesu wá tún pa òwe yìí fún wọn. Ó ní, “Afọ́jú kò lè fi ọ̀nà han afọ́jú. Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, inú kòtò ni àwọn mejeeji yóo bá ara wọn. Ọmọ-ẹ̀yìn kò ju olùkọ́ rẹ̀ lọ. Ṣugbọn bí ọmọ-ẹ̀yìn bá jáfáfá yóo dàbí olùkọ́ rẹ̀. “Kí ló dé tí o fi ń wo ẹ̀ẹ́rún igi tí ó wà lójú arakunrin rẹ, nígbà tí o kò ṣe akiyesi ìtì igi ńlá tí ó wà lójú ìwọ alára? Báwo ni o ṣe lè wí fún arakunrin rẹ pé, ‘Ọ̀rẹ́, jẹ́ kí n bá ọ yọ ẹ̀ẹ́rún igi tí ó wà lójú rẹ,’ nígbà tí o kò rí ìtì igi tí ó wà lójú ara rẹ? Ìwọ a-rí-tẹni-mọ̀-ọ́n-wí, kọ́kọ́ yọ ìtì igi kúrò lójú ara rẹ, nígbà náà, ìwọ óo ríran kedere láti lè yọ ẹ̀ẹ́rún igi tí ó wà lójú arakunrin rẹ. “Igi rere kò lè so èso burúkú. Bẹ́ẹ̀ ni igi burúkú kò lé so èso rere. Èso tí igi kan bá so ni a óo fi mọ̀ ọ́n. Nítorí eniyan kò lè ká èso ọ̀pọ̀tọ́ lórí igi ẹlẹ́gùn-ún. Bẹ́ẹ̀ ni eniyan kò lè rí èso ọsàn lórí igi ọdán. Eniyan rere ń mú ohun rere wá láti inú orísun rere ọkàn rẹ̀. Eniyan burúkú ń mú nǹkan burúkú jáde láti inú ọkàn burúkú rẹ̀. Nítorí ohun tí ó bá wà ninu ọkàn ẹni ni ẹnu ẹni ń sọ jáde. “Kí ló dé tí ẹ̀ ń pè mí ní, ‘Oluwa, Oluwa,’ tí ẹ kì í ṣe ohun tí mo sọ? Ẹni tí ó bá wá sọ́dọ̀ mi, tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó ń ṣe é, n óo sọ fun yín ẹni tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ jọ. Ó dàbí ọkunrin kan tí ó ń kọ́ ilé, tí ó wa ìpìlẹ̀ rẹ̀ tí ó jìn, tí ó wá fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé orí àpáta. Nígbà tí ìkún omi dé, tí àgbàrá bì lu ilé náà, kò lè mì ín, nítorí wọ́n kọ́ ọ dáradára. Ṣugbọn ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí kò ṣe é, ó dàbí ọkunrin kan tí ó ń kọ́ ilé kalẹ̀ láì ní ìpìlẹ̀. Nígbà tí àgbàrá bì lù ú, lẹsẹkẹsẹ ni ó wó, ó sì wó kanlẹ̀ patapata.” Nígbà tí Jesu parí ọ̀rọ̀ tí ó ń bá àwọn eniyan sọ, ó wọ inú ìlú Kapanaumu lọ. Ọ̀gágun kan ní ẹrú kan tí ó ṣàìsàn, ó fẹ́rẹ̀ kú. Ẹrú náà ṣe ọ̀wọ́n fún un. Nígbà tí ó gbọ́ nípa Jesu, ó rán àwọn àgbààgbà Juu kan sí i pé kí wọn bá òun bẹ̀ ẹ́ kí ó wá wo ẹrú òun sàn. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu wọ́n ń bẹ̀ ẹ́ pé kí ó tètè. Wọ́n ní, “Ọ̀gágun náà yẹ ní ẹni tí o lè ṣe èyí fún, nítorí ó fẹ́ràn orílẹ̀-èdè wa, òun fúnrarẹ̀ ni ó kọ́ ilé ìpàdé fún wa.” Jesu bá ń bá wọn lọ. Ṣugbọn nígbà tí ó ṣì wà ní ọ̀nà jíjìn sí ilé ọ̀gágun náà, ọ̀gágun náà rán àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sí Jesu kí wọ́n sọ pé, “Alàgbà, má ṣe ìyọnu. Èmi kò yẹ ní ẹni tí ìwọ ìbá wọ ilé rẹ̀. Òun ni kò jẹ́ kí èmi fúnra mi wá sọ́dọ̀ rẹ. Ṣugbọn sọ gbolohun kan, ara ọmọ-ọ̀dọ̀ mi yóo sì dá. Nítorí èmi náà jẹ́ ẹni tí ó wà lábẹ́ àṣẹ. Mo ní àwọn ọmọ-ogun lábẹ́ mi. Bí mo bá sọ fún ọ̀kan pé, ‘Lọ!’ Yóo lọ ni. Bí mo bá sì sọ fún òmíràn pé, ‘Wá!’ Yóo wá ni. Bí mo bá sọ fún ẹrú mi pé, ‘Ṣe èyí!’ Yóo ṣe é ni.” Nígbà tí Jesu gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹnu yà á. Ó bá yipada sí àwọn eniyan tí ó ń tẹ̀lé e, ó ní, “Mò ń sọ fun yín, n kò rí irú igbagbọ báyìí ní Israẹli pàápàá!” Nígbà tí àwọn tí ọ̀gágun rán pada dé ilé, wọ́n rí ẹrú náà tí ara rẹ̀ ti dá. Láìpẹ́ lẹ́yìn èyí, Jesu lọ sí ìlú kan tí ń jẹ́ Naini. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ati ọ̀pọ̀ eniyan ń bá a lọ. Nígbà tí wọ́n súnmọ́ ẹnu odi ìlú náà, wọ́n rí òkú ọmọ kan tí wọn ń gbé jáde. Ọmọ yìí nìkan náà ni ìyá rẹ̀ bí. Opó sì ni ìyá náà. Ọ̀pọ̀ àwọn eniyan láti inú ìlú wá pẹlu obinrin náà. Nígbà tí Oluwa rí obinrin náà, àánú rẹ̀ ṣe é. Ó sọ fún un pé, “Má sunkún mọ́.” Ni ó bá lọ, ó fi ọwọ́ kan pósí. Àwọn tí wọ́n gbé pósí bá dúró. Ó bá sọ pé, “Ọdọmọkunrin, mo sọ fún ọ, dìde.” Ọdọmọkunrin tí ó ti kú yìí bá dìde jókòó, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀. Jesu bà fà á lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́. Ẹ̀rù ba gbogbo eniyan, wọ́n fi ògo fún Ọlọrun, wọ́n ní, “Wolii ńlá ti dìde ni ààrin wa. Ọlọrun ti bojúwo àwọn eniyan rẹ̀.” Ìròyìn ohun tí ó ṣe yìí tàn ká gbogbo Judia ati gbogbo agbègbè ibẹ̀. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ròyìn gbogbo nǹkan wọnyi fún un. Johanu bá pe meji ninu wọn, ó rán wọn sí Oluwa láti bi í pé, “Ṣé ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀ ni, tabi kí á máa retí ẹlòmíràn?” Nígbà tí àwọn ọkunrin náà dé ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n ní, “Johanu Onítẹ̀bọmi ni ó rán wa sí ọ láti bi ọ́ pé, ‘Ṣé ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀ ni, tabi kí á máa retí ẹlòmíràn?’ ” Ní àkókò náà, Jesu ń wo ọpọlọpọ eniyan sàn ninu àìsàn ati àrùn. Ó ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ọpọlọpọ àwọn afọ́jú ni ó jẹ́ kí wọ́n ríran. Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ lọ sọ ohun tí ẹ rí ati ohun tí ẹ gbọ́ fún Johanu: àwọn afọ́jú ń ríran; àwọn arọ ń rìn, ara àwọn adẹ́tẹ̀ ń di mímọ́; àwọn adití ń gbọ́ràn, à ń jí àwọn òkú dìde; à ń waasu ìyìn rere fún àwọn talaka. Ẹni tí kò bá ṣiyèméjì nípa mi ṣe oríire!” Lẹ́yìn tí àwọn oníṣẹ́ Johanu lọ tán, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀ nípa Johanu fún àwọn eniyan. Ó ní, “Kí ni ẹ jáde lọ wò ní aṣálẹ̀? Igi légbélégbé tí afẹ́fẹ́ ń tì sọ́tùn-ún, ati sósì ni bí? Kí ni ẹ jáde lọ wò? Ọkunrin tí ó wọ aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ olówó iyebíye ni bí? Bí ẹ bá fẹ́ rí àwọn tí ó wọ aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ olówó iyebíye, ẹ lọ sí ààfin ọba. Àní, kí ni ẹ lọ wò? Wolii ni bí? Bẹ́ẹ̀ ni. Mo sọ fun yín, ó tilẹ̀ ju wolii lọ! Òun ni a kọ nípa rẹ̀ pé, ‘Wò ó! Mo rán oníṣẹ́ mi ṣiwaju rẹ, òun ni yóo palẹ̀ mọ́ dè ọ́.’ Mo sọ fun yín pé, kò sí ẹnikẹ́ni jákèjádò ayé yìí tí ó ṣe pataki ju Johanu lọ. Sibẹ, ẹni tí ó kéré jùlọ ninu ìjọba ọ̀run ṣe pataki jù ú lọ.” Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan gbọ́, tí ó fi mọ́ àwọn agbowó-odè pàápàá, wọ́n fi ìyìn fún Ọlọrun, wọ́n lọ ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ètò ìrìbọmi Johanu. Ṣugbọn àwọn Farisi ati àwọn amòfin kọ ìlànà Ọlọrun fún wọn, wọn kò ṣe ìrìbọmi ti Johanu. Jesu tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ bọ̀, ó ní, “Ta ni èmi ìbá fi àwọn eniyan òde òní wé? Ta ni kí a wí pé wọ́n jọ? Wọ́n jọ àwọn ọmọde tí wọ́n jókòó ní ọjà. Àwọn kan ń pe àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn pé, ‘A lù fun yín, ẹ kò jó, A sun rárà òkú fun yín, ẹ kò sunkún.’ Nítorí Johanu Onítẹ̀bọmi dé, kò jẹ, kò mu, ẹ sọ pé, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù ni.’ Ọmọ-Eniyan dé, ó ń jẹ, ó ń mu, ẹ ní, ‘Ẹ kò rí ọkunrin yìí, oníjẹkújẹ ati ọ̀mùtí, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.’ Sibẹ a mọ̀ pé ọgbọ́n Ọlọrun tọ̀nà nípa ìṣesí gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀.” Ọ̀kan ninu àwọn Farisi pe Jesu pé kí ó wá bá òun jẹun. Jesu bà lọ sí ilé Farisi yìí lọ jẹun. Obinrin kan báyìí wà ninu ìlú tí ó gbọ́ pé Jesu ń jẹun ní ilé Farisi, ó mú ìgò òróró olóòórùn dídùn lọ́wọ́, ó lọ dúró lẹ́yìn lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó ń sunkún, omijé rẹ̀ ń dà sí ẹsẹ̀ Jesu, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi irun rẹ̀ nù ún, ó ń fi ẹnu kan ẹsẹ̀ Jesu, ó tún ń fi òróró kùn ún lẹ́sẹ̀. Nígbà tí Farisi tí ó pe Jesu wá jẹun rí i, ó rò ninu ara rẹ̀ pé, “Ìbá jẹ́ pé wolii ni ọkunrin yìí, ìbá ti mọ irú ẹni tí obinrin yìí tí ó ń fọwọ́ kàn án jẹ́, nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.” Jesu sọ fún un pé, “Simoni, mo fẹ́ bi ọ́ léèrè ọ̀rọ̀ kan.” Simoni ní, “Olùkọ́ni, máa wí.” Jesu ní, “Àwọn meji kan jẹ gbèsè. Wọ́n yá owó lọ́wọ́ ẹnìkan tí í máa ń yá eniyan lówó pẹlu èlé. Ọ̀kan jẹ ẹ́ ní àpò marun-un owó fadaka, ekeji jẹ ẹ́ ní aadọta owó fadaka. Nígbà tí wọn kò rí ọ̀nà ati san gbèsè wọn, ẹni tí ó yá wọn lówó bùn wọ́n ní owó náà. Ninu àwọn mejeeji, ta ni yóo fẹ́ràn rẹ̀ jù?” Simoni dáhùn pé, “Ẹni tí ó fún ni owó pupọ ni.” Jesu wá sọ fún un pé, “O wí ire.” Jesu bá yipada sí obinrin náà, ó sọ fún Simoni pé, “Ṣé o rí obinrin yìí? Mo wọ ilé rẹ, o kò fún mi ní omi kí n fi fọ ẹsẹ̀. Ṣugbọn obinrin yìí fi omijé rẹ̀ fọ ẹsẹ̀ mi, ó sì fi irun orí rẹ̀ nù ún. O kò fi ìfẹnukonu kí mi. Ṣugbọn obinrin yìí kò dẹ́kun láti fi ẹnu kan ẹsẹ̀ mi láti ìgbà tí mo ti wọ ilé. O kò fi òróró kùn mí lórí. Ṣugbọn obinrin yìí fi òróró olóòórùn dídùn kùn mí lẹ́sẹ̀. Nítorí èyí, mo sọ fún ọ, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó pọ̀ jì í, nítorí ó ní ìfẹ́ pupọ. Ṣugbọn ẹni tí a bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ díẹ̀ jì, ìfẹ́ díẹ̀ ni yóo ní.” Ó bá sọ fún obinrin náà pé, “A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.” Àwọn tí wọ́n jọ ń jẹun bà bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Ta ni eléyìí tí ó ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan?” Jesu bá sọ fún obinrin náà pé, “Igbagbọ rẹ ti gbà ọ́ là. Máa lọ ní alaafia.” Lẹ́yìn èyí, Jesu ń rìn káàkiri láti ìlú dé ìlú, ati láti abúlé dé abúlé. Ó ń waasu ìyìn rere ìjọba Ọlọrun. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila ń bá a kiri. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn obinrin kan tí Jesu ti wòsàn kúrò ninu ẹ̀mí èṣù ati àìlera ń bá a kiri. Ninu wọn ni Maria tí à ń pè ní Magidaleni wà, tí Jesu lé ẹ̀mí èṣù meje jáde ninu rẹ̀, ati Joana iyawo Kusa, ọmọ-ọ̀dọ̀ Hẹrọdu, ati Susana ati ọpọlọpọ àwọn mìíràn. Àwọn yìí ni wọ́n ń fi ohun ìní wọn bá Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ bùkátà wọn. Ọpọlọpọ eniyan ń wọ́ tẹ̀lé e lẹ́yìn láti ìlú dé ìlú. Ó wá fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé: “Afunrugbin kan jáde lọ láti fúnrúgbìn. Bí ó ti ń fúnrúgbìn, irúgbìn díẹ̀ bọ̀ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ bá wá, wọ́n ṣà á jẹ. Irúgbìn mìíràn bọ́ sórí àpáta. Nígbà tí ó hù, ó bá gbẹ nítorí kò sí omi. Irúgbìn mìíràn bọ́ sáàrin ẹ̀gún. Nígbà tí òun ati ẹ̀gún jọ dàgbà, ń ṣe ni ẹ̀gún fún un pa. Irúgbìn mìíràn bọ́ sórí ilẹ̀ dáradára, ó dàgbà, ó sì so èso. Irúgbìn kọ̀ọ̀kan so ọgọọgọrun-un.” Nígbà tí ó sọ báyìí tán, ó wá tún sọ pé, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́!” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bi í ní ìtumọ̀ òwe yìí. Ó ní, “Ẹ̀yin ni a fi fún láti mọ àṣírí ìjọba Ọlọrun, ṣugbọn fún àwọn yòókù, bí òwe bí òwe ni, pé wọn yóo máa wo nǹkan ṣugbọn wọn kò ní mọ ohun tí wọn rí, wọn yóo máa gbọ́ràn ṣugbọn òye ohun tí wọn gbọ́ kò ní yé wọn. “Ìtumọ̀ òwe yìí nìyí: irúgbìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Àwọn tí ó bọ́ sẹ́bàá ọ̀nà ni àwọn tí wọ́n gbọ́, lẹ́yìn náà èṣù wá, ó mú ọ̀rọ̀ náà kúrò ní ọkàn wọn, kí wọn má baà gbàgbọ́, kí a sì gbà wọ́n là. Àwọn tí ó bọ́ sórí òkúta ni àwọn tí ó gbọ́, tí wọ́n fi tayọ̀tayọ̀ gba ọ̀rọ̀ náà, ṣugbọn wọn kò ní gbòǹgbò. Wọ́n gbàgbọ́ fún àkókò díẹ̀. Ṣugbọn nígbà tí ìdánwò dé, wọ́n bọ́hùn. Àwọn tí ó bọ́ sáàrin ẹ̀gún ni àwọn tí ó gbọ́, ṣugbọn àkólékàn ayé, ìlépa ọrọ̀, ati ìgbádùn ayé fún ọ̀rọ̀ náà pa, wọn kò lè dàgbà láti so èso. Àwọn ti ilẹ̀ dáradára ni àwọn tí ó fi ọkàn rere ati ọkàn mímọ́ gba ọ̀rọ̀ náà, wọ́n sì dì í mú ṣinṣin, wọ́n sì so èso nípa ìfaradà. “Kò sí ẹnìkan tí ó jẹ́ tan fìtílà tán, kí ó fi àwo bò ó mọ́lẹ̀, tabi kí ó gbé e sábẹ́ ibùsùn. Orí ọ̀pá fìtílà ni wọ́n ń gbé e kà, kí gbogbo ẹni tí ó bá ń wọlé lè ríran. “Nítorí kò sí ohun kan tí ó pamọ́ tí kò ní fara hàn, kò sì sí nǹkan bòńkẹ́lẹ́ kan tí eniyan kò ní mọ̀. “Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra nípa bí ẹ ti ṣe ń gbọ́ràn, nítorí ẹni tí ó bá ní ni a óo tún fún sí i, ṣugbọn lọ́wọ́ ẹni tí kò bá ní ni a óo ti gba ìwọ̀nba tí ó rò pé òun ní.” Ìyá Jesu ati àwọn arakunrin rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ṣugbọn wọn kò lè dé ibi tí ó wà nítorí ọ̀pọ̀ eniyan. Àwọn eniyan bá sọ fún un pé, “Ìyá rẹ ati àwọn arakunrin rẹ dúró lóde, wọ́n fẹ́ fi ojú kàn ọ́.” Ṣugbọn Jesu wí fún gbogbo wọn pé, “Ìyá mi ati àwọn arakunrin mi ni àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun, tí wọ́n sì ń ṣe é.” Ní ọjọ́ kan Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ inú ọkọ̀ ojú omi kan, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á kọjá lọ sí òdìkejì òkun.” Ni wọ́n bá lọ. Bí wọ́n ti ń wakọ̀ lọ, Jesu bá sùn lọ. Ìjì líle kan bá bẹ̀rẹ̀ lójú òkun, omi bẹ̀rẹ̀ sí ya wọ inú ọkọ̀; ẹ̀mí wọn sì wà ninu ewu. Ni wọ́n bá lọ jí Jesu, wọ́n ní, “Ọ̀gá! Ọ̀gá! Ọkọ̀ mà ń rì lọ!” Ni Jesu bá dìde, ó bá afẹ́fẹ́ ati ìgbì omi wí, ni ìgbì bá rọlẹ̀, gbogbo nǹkan bá dákẹ́ jẹ́. Ó bá bi wọ́n pé, “Igbagbọ yín dà?” Pẹlu ìbẹ̀rù ati ìyanu, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn sọ pé, “Ta nì yìí? Ó pàṣẹ fún afẹ́fẹ́ ati ìgbì omi, wọ́n sì ń gbọ́ràn sí i lẹ́nu!” Wọ́n gúnlẹ̀ sí ilẹ̀ àwọn ará Geraseni tí ó wà ní òdì keji òkun tí ó dojú kọ ilẹ̀ Galili. Bí ó ti bọ́ sí èbúté, ọkunrin kan tí ó ní ẹ̀mí èṣù jáde láti inú ìlú wá pàdé rẹ̀. Ó ti pẹ́ tí ó ti fi aṣọ kanra gbẹ̀yìn, kò sì lè gbé inú ilé mọ́, àfi ní itẹ́ òkú. Nígbà tí ó rí Jesu, ó kígbe, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó kébòòsí pé, “Kí ni ó pa èmi ati ìwọ pọ̀, Jesu, ọmọ Ọlọrun Ọ̀gá Ògo? Mo bẹ̀ ọ́ má dá mi lóró!” Nítorí Jesu ti pàṣẹ fún ẹ̀mí àìmọ́ náà láti jáde kúrò ninu ọkunrin yìí. Nítorí ní ọpọlọpọ ìgbà ní í máa ń dé sí i. Wọn á fi ẹ̀wọ̀n dè é lọ́wọ́, wọn á tún kó ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ sí i lẹ́sẹ̀. Ṣugbọn jíjá ni yóo já ohun tí wọ́n fi dè é, ni yóo bá sálọ sinu aṣálẹ̀. Jesu bi í pé, “Kí ni orúkọ rẹ?” Ó ní, “Ẹgbaagbeje,” Nítorí àwọn ẹ̀mí èṣù tí ó ti wọ inú rẹ̀ pọ̀. Àwọn ẹ̀mí èṣù yìí bá bẹ Jesu pé kí ó má lé àwọn lọ sinu ọ̀gbun àìnísàlẹ̀. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ kan wà níbẹ̀ tí ó ń jẹ lórí òkè. Àwọn ẹ̀mí náà bẹ̀ ẹ́ pé kí ó jẹ́ kí àwọn kó sí inú agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà. Ó bá gbà fún wọn. Àwọn ẹ̀mí èṣù yìí bá jáde kúrò ninu ọkunrin tí à ń wí yìí, wọ́n wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀, ni agbo ẹlẹ́dẹ̀ bá sáré láti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè lọ sí inú òkun, wọ́n bá rì sómi. Nígbà tí àwọn tí ń tọ́jú agbo ẹlẹ́dẹ̀ rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n bá sá kúrò níbẹ̀, wọ́n lọ ròyìn ní ìlú ati ní ìgbèríko. Àwọn eniyan bà jáde láti lọ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n rí ọkunrin tí àwọn ẹ̀mí èṣù jáde ninu rẹ̀, tí ó jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó wọ aṣọ, ojú rẹ̀ sì wálẹ̀. Ẹ̀rù ba àwọn eniyan. Àwọn tí ó mọ̀ bí ara ọkunrin náà ti ṣe dá ròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún wọn. Gbogbo àwọn eniyan agbègbè Geraseni bá bẹ Jesu pé kí ó kúrò lọ́dọ̀ àwọn nítorí ẹ̀rù bà wọ́n pupọ. Ó bá tún wọ inú ọkọ̀ ojú omi, ó pada sí ibi tí ó ti wá. Ọkunrin tí àwọn ẹ̀mí èṣù jáde ninu rẹ̀ bẹ Jesu pé kí ó jẹ́ kí òun máa wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Ṣugbọn Jesu kọ̀ fún un, ó ní, “Pada lọ sí ilé rẹ, kí o lọ ròyìn ohun tí Ọlọrun ṣe fún ọ.” Ni ọkunrin náà bá ń káàkiri gbogbo ìlú, ó ròyìn ohun tí Jesu ṣe fún un. Nígbà tí Jesu pada dé, àwọn eniyan fi tayọ̀tayọ̀ gbà á, nítorí gbogbo wọn ti ń retí rẹ̀. Ọkunrin kan tí ó ń jẹ́ Jairu, tí ó jẹ́ alákòóso ilé ìpàdé, wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó wólẹ̀ níwájú Jesu, ó bẹ̀ ẹ́ pé kí ó bá òun kálọ sí ilé, nítorí ọmọdebinrin rẹ̀ kan ṣoṣo tí ó ní ń kú lọ. Ọmọ yìí tó ọmọ ọdún mejila. Bí Jesu ti ń lọ àwọn eniyan ń bì lù ú níhìn-ín lọ́hùn-ún. Obinrin kan wà tí nǹkan oṣù rẹ̀ kọ̀, tí kò dá fún ọdún mejila. Ó ti ná gbogbo ohun tí ó ní fún àwọn oníṣègùn ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò lè wò ó sàn. Ó bá gba ẹ̀yìn wá, ó fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí ẹ̀wù Jesu, lẹsẹkẹsẹ ìsun ẹ̀jẹ̀ náà bá dá lára rẹ̀. Jesu ní, “Ta ni fọwọ́ kàn mí?” Nígbà tí gbogbo wọn sẹ́, Peteru ní, “Ọ̀gá, mélòó-mélòó ni àwọn eniyan tí wọn ń fún ọ, tí wọn ń tì ọ́?” Ṣugbọn Jesu tún tẹnu mọ́ ọn pé, “Ẹnìkan fọwọ́ kàn mí sẹ́ẹ̀, nítorí mo mọ̀ pé agbára ti ara mi jáde.” Nígbà tí obinrin náà rí i pé kò ṣe é fi pamọ́, ó bá jáde, ó ń gbọ̀n. Ó kúnlẹ̀ níwájú Jesu, ó bá sọ ìdí tí òun ṣe fọwọ́ kàn án lójú gbogbo eniyan ati bí òun ṣe rí ìwòsàn lẹsẹkẹsẹ. Jesu wá wí fún un pé, “Ọmọbinrin, igbagbọ rẹ ti mú ọ lára dá, máa lọ ní alaafia.” Bí ó ti ń sọ̀rọ̀, àwọn kan wá láti ọ̀dọ̀ alákòóso ilé ìpàdé, wọ́n ní, “Ọdọmọdebinrin rẹ ti kú. Má wulẹ̀ yọ olùkọ́ni lẹ́nu mọ́.” Ṣugbọn nígbà tí Jesu gbọ́, ó dá a lóhùn pé, “Má bẹ̀rù, ṣá gbàgbọ́, ara ọmọ rẹ yóo dá.” Nígbà tí Jesu dé ilé, kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọlé àfi Peteru, Johanu ati Jakọbu, baba ati ìyá ọmọ náà. Gbogbo àwọn eniyan ń sunkún, wọ́n ń dárò nítorí ọmọ náà. Ṣugbọn Jesu ní, “Ẹ má sunkún mọ́, nítorí ọmọ náà kò kú, ó ń sùn ni.” Ńṣe ni wọ́n ń fi Jesu rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà, nítorí wọ́n mọ̀ pé ọmọ náà ti kú. Jesu fa ọmọ náà lọ́wọ́, ó sọ fún un pé, “Ọmọ, dìde.” Ẹ̀mí rẹ̀ bá pada sinu rẹ̀, ni ó bá dìde lẹsẹkẹsẹ. Jesu bá sọ fún wọn pé kí wọn fún un ní oúnjẹ. Ẹnu ya àwọn òbí ọmọ náà. Ṣugbọn ó kìlọ̀ fún wọn pé kí wọn má ṣe sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún ẹnikẹ́ni. Jesu pe àwọn mejila jọ. Ó fún wọn ní agbára ati àṣẹ láti lé gbogbo ẹ̀mí èṣù jáde ati láti ṣe ìwòsàn oríṣìíríṣìí àìsàn. Ó rán wọn láti waasu ìjọba Ọlọrun ati láti ṣe ìwòsàn. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe mú nǹkankan lọ́wọ́ lọ ìrìn àjò yìí: ẹ má mú ọ̀pá lọ́wọ́, tabi àpò báárà tabi oúnjẹ tabi owó, tabi àwọ̀tẹ́lẹ̀ meji. Ilé tí ẹ bá wọ̀ sí, níbẹ̀ ni kí ẹ máa gbé títí ẹ óo fi kúrò ní ìlú náà. Ibikíbi tí wọn kò bá ti gbà yín, nígbà tí ẹ bá jáde kúrò ninu ìlú náà, ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí sí wọn.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bá ń lọ láti abúlé dé abúlé, wọ́n ń waasu ìyìn rere, wọ́n sì ń ṣe ìwòsàn níbi gbogbo. Nígbà tó yá, Hẹrọdu, baálẹ̀, gbọ́ nípa gbogbo nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀, ó dààmú; nítorí àwọn kan ń sọ pé Johanu ni ó jí dìde kúrò ninu òkú. Ṣugbọn àwọn mìíràn ń sọ pé Elija ni ó fara hàn. Àwọn mìíràn ní ọ̀kan ninu àwọn wolii àtijọ́ ni ó tún pada. Ṣugbọn Hẹrọdu ní “Ní ti Johanu, mo ti bẹ́ ẹ lórí. Ta wá ni òun, tí mò ń gbọ́ gbogbo nǹkan wọnyi nípa rẹ̀?” Hẹrọdu bá ń wá ọ̀nà láti fojú kàn án. Àwọn aposteli tí Jesu rán níṣẹ́ pada wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ròyìn gbogbo ohun tí wọ́n ti ṣe fún un. Ó bá rọra dá àwọn nìkan mú lọ sí ìlú kan tí ń jẹ́ Bẹtisaida. Ṣugbọn àwọn eniyan mọ̀, ni wọ́n bá tẹ̀lé e. Ó gbà wọ́n pẹlu ayọ̀, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ìjọba Ọlọrun, ó tún ń wo àwọn aláìsàn sàn. Nígbà tí ọjọ́ rọ̀, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila sọ fún un pé, “Tú àwọn eniyan wọnyi ká kí wọ́n lè lọ sí àwọn abúlé káàkiri ati àwọn ìletò láti wọ̀ sí ati láti wá oúnjẹ, nítorí aṣálẹ̀ ni ibi tí a wà yìí.” Ṣugbọn Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni kí ẹ fún wọn ní oúnjẹ.” Wọ́n dáhùn pé, “A kò ní oúnjẹ pupọ, àfi burẹdi marun-un ati ẹja meji, ṣé kí àwa fúnra wa lọ ra oúnjẹ fún gbogbo àwọn eniyan wọnyi ni?” (Àwọn ọkunrin ninu wọn tó bíi ẹgbẹẹdọgbọn (5,000).) Ó bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí wọ́n jókòó ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ bí araadọta.” Wọ́n bá ṣe bí ó ti wí: wọ́n fi gbogbo wọn jókòó. Jesu bá mú burẹdi marun-un yìí ati ẹja meji, ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó gbadura sí i, ó pín wọn sí wẹ́wẹ́, ó bá fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n fún àwọn eniyan. Gbogbo àwọn eniyan jẹ, wọ́n yó. Wọ́n kó àjẹkù jọ, ó sì kún apẹ̀rẹ̀ mejila. Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Jesu nìkan ń dá gbadura tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Ó bi wọ́n pé, “Ta ni àwọn eniyan rò pé mo jẹ́?” Wọ́n dáhùn pé, “Àwọn kan ní Johanu Onítẹ̀bọmi ni ọ́, ṣugbọn àwọn mìíràn ní, Elija ni ọ. Àwọn mìíràn tún sọ pé ọ̀kan ninu àwọn wolii àtijọ́ ni ó jí dìde.” Ó wá bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ńkọ́? Ta ni ẹ rò pé mo jẹ́?” Peteru dáhùn pé, “Mesaya Ọlọrun ni ọ́.” Jesu wá kìlọ̀ fún wọn kí wọn má sọ fún ẹnikẹ́ni. Ó ní, “Dandan ni kí Ọmọ-Eniyan jìyà pupọ, kí àwọn àgbà ati àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin kọ̀ ọ́, kí wọ́n sì pa á, ṣugbọn a óo jí i dìde ní ọjọ́ kẹta.” Ó bá sọ fún gbogbo àwọn eniyan pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ máa tẹ̀lé mí, ó níláti sẹ́ ara rẹ̀, kí ó gbé agbelebu rẹ̀ lojoojumọ, kí ó wá máa tọ̀ mí lẹ́yìn. Nítorí pé ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là, yóo pàdánù rẹ̀, ṣugbọn ẹni tí ó bá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nítorí mi, òun ni yóo gba ẹ̀mí rẹ̀ là. Nítorí anfaani wo ni ó jẹ́ fún ẹnikẹ́ni, bí ó bá jèrè gbogbo ayé, ṣugbọn tí ó pàdánù ẹ̀mí ara rẹ̀? Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá tijú mi ati àwọn ọ̀rọ̀ mi, òun ni Ọmọ-Eniyan yóo tijú nígbà tí ó bá dé ninu ògo rẹ̀ ati ògo Baba rẹ̀, pẹlu àwọn angẹli mímọ́. Ṣugbọn mo sọ fun yín dájúdájú, àwọn mìíràn wà ninu àwọn tí ó dúró níhìn-ín tí wọn kò ní kú títí wọn óo fi rí ìjọba Ọlọrun.” Ó tó bí ọjọ́ mẹjọ lẹ́yìn tí ọ̀rọ̀ yìí ṣẹlẹ̀, Jesu mú Peteru, Johanu ati Jakọbu lọ sí orí òkè kan láti gbadura. Bí ó ti ń gbadura, ìwò ojú rẹ̀ yipada, aṣọ rẹ̀ wá funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Àwọn ọkunrin meji kan yọ lójijì, wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀. Àwọn ni Mose ati Elija. Wọ́n farahàn ninu ògo, wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀ nípa irú ikú tí yóo kú láìpẹ́, ní Jerusalẹmu. Ṣugbọn oorun ti ń kun Peteru ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀. Nígbà tí wọ́n tají, wọ́n rí ògo rẹ̀ ati àwọn ọkunrin meji tí wọ́n dúró tì í. Bí àwọn meji yìí ti ń kúrò lọ́dọ̀ Jesu, Peteru sọ fún un pé, “Ọ̀gá, ìbá dára tí a bá lè máa wà níhìn-ín. Jẹ́ kí á pa àgọ́ mẹta, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mose, ati ọ̀kan fún Elija.” Ó sọ èyí nítorí kò mọ ohun tíì bá sọ. Bí ó ti ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, ìkùukùu bá ṣíji bò wọ́n. Ẹ̀rù ba Peteru ati Johanu ati Jakọbu nígbà tí Mose ati Elija wọ inú ìkùukùu náà. Ohùn kan ti inú ìkùukùu náà wá, ó ní “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹ máa gbọ́ tirẹ̀!” Bí wọ́n ti gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, Jesu nìkan ni wọ́n rí. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bá pa ẹnu mọ̀, wọn kò sọ ohun tí wọ́n gbọ́ ati ohun tí wọ́n rí ní àkókò náà fún ẹnikẹ́ni. Ní ọjọ́ keji, lẹ́yìn tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, ọ̀pọ̀ eniyan wá pàdé rẹ̀. Ọkunrin kan ninu àwùjọ kígbe pé, “Olùkọ́ni, mo bẹ̀ ọ́, ṣàánú ọmọ mi, nítorí òun nìkan ni mo bí. Ẹ̀mí kan a máa gbé e. Lójijì yóo kígbe tòò, ara rẹ̀ óo le gbandi. Yóo bá máa yọ ìfòòfó lẹ́nu, ni ẹ̀mí yìí yóo bá gbé e ṣánlẹ̀; kò sì ní tètè fi í sílẹ̀. Mo bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ pé kí wọ́n lé e jáde, ṣugbọn wọn kò lè ṣe é.” Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin ìran oníbàjẹ́ ati alaigbagbọ yìí! N óo ti wà pẹlu yín pẹ́ tó! N óo ti fara dà á fun yín tó! Mú ọmọ rẹ wá síhìn-ín.” Bí ó ti ń mú un bọ̀, ẹ̀mí èṣù yìí bá gbé e ṣánlẹ̀, wárápá bá mú un. Jesu bá bá ẹ̀mí èṣù náà wí, ó wo ọmọ náà sàn, ó bá fà á lé baba rẹ̀ lọ́wọ́. Ẹnu ya gbogbo eniyan sí iṣẹ́ ńlá Ọlọrun. Bí ẹnu ti ń ya gbogbo eniyan sí gbogbo ohun tí Jesu ń ṣe, ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ wọnyi wọ̀ yín létí. Ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò tí a óo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn eniyan lọ́wọ́.” Ṣugbọn gbolohun yìí kò yé wọn, nítorí a ti fi ìtumọ̀ rẹ̀ pamọ́ fún wọn, kí ó má baà yé wọn. Ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti bi í nípa ọ̀rọ̀ yìí. Àríyànjiyàn kan bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu lórí pé ta ló ṣe pataki jùlọ láàrin wọn. Jesu mọ ohun tí wọn ń rò lọ́kàn. Ó bá mú ọmọde kan, ó gbé e dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ó wí fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọmọde yìí ní orúkọ mi, èmi ni ó gbà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbà mí, gba ẹni tí ó fi iṣẹ́ rán mi. Nítorí ẹni tí ó kéré jùlọ ninu yín, òun ló jẹ́ eniyan pataki jùlọ.” Johanu sọ fún un pé, “Ọ̀gá, a rí ẹnìkan tí ń fi orúkọ rẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. A fẹ́ dá a lẹ́kun nítorí kì í ṣe ara wa.” Ṣugbọn Jesu sọ fún un pé. “Ẹ má dá a lẹ́kun, nítorí ẹni tí kò bá lòdì si yín, tiyín ní ń ṣe.” Nígbà tí ó tó àkókò tí a óo gbé Jesu lọ sókè ọ̀run, ọkàn rẹ̀ mú un láti lọ sí Jerusalẹmu. Ó bá rán àwọn oníṣẹ́ ṣiwaju rẹ̀. Wọ́n bá wọ inú ìletò àwọn ará Samaria kan láti ṣe ètò sílẹ̀ dè é. Ṣugbọn wọn kò gbà á, nítorí ó hàn dájú pé ó ń lọ sí Jerusalẹmu. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Jakọbu ati Johanu, rí i, wọ́n ní, “Oluwa, ṣé o fẹ́ kí á pe iná láti ọ̀run kí ó jó wọn pa?” Ṣugbọn Jesu yipada, ó bá wọn wí. Ni wọ́n bá lọ sí ìletò mìíràn. Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, ẹnìkan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “N óo máa bá ọ lọ sí ibikíbi tí o bá ń lọ.” Jesu dá a lóhùn pé, “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ìtẹ́, ṣugbọn Ọmọ-Eniyan kò ní ibi tí yóo gbé orí rẹ̀ lé.” Ó bá sọ fún ẹlòmíràn pé, “Máa tẹ̀lé mi.” Ṣugbọn onítọ̀hún dáhùn pé, “Alàgbà, jẹ́ kí n kọ́ lọ sìnkú baba mi ná.” Ṣugbọn Jesu sọ fún un pé, “Jẹ́ kí àwọn òkú máa sin òkú ara wọn. Ìwọ ní tìrẹ, wá máa waasu ìjọba Ọlọrun.” Ẹlòmíràn tún sọ fún un pé, “N óo tẹ̀lé ọ Oluwa. Ṣugbọn jẹ́ kí n kọ́kọ́ lọ dágbére fún àwọn ará ilé mi.” Ṣugbọn Jesu sọ pé, “Kò sí ẹni tí ó bá ti dá ọwọ́ lé lílo ẹ̀rọ-ìroko, tí ó bá tún ń wo ẹ̀yìn tí ó yẹ fún ìjọba Ọlọrun.” Lẹ́yìn èyí, Oluwa yan àwọn mejilelaadọrin mìíràn, ó rán wọn ní meji-meji ṣiwaju rẹ̀ lọ sí gbogbo ìlú ati ibi tí òun náà fẹ́ dé. Ó sọ fún wọn pé, “Àwọn nǹkan tí ó tó kórè pọ̀ ninu oko, ṣugbọn àwọn òṣìṣẹ́ kò pọ̀ tó. Nítorí náà, ẹ bẹ Oluwa ìkórè kí ó rán àwọn alágbàṣe sí ibi ìkórè rẹ̀. Ẹ máa lọ. Mo ran yín lọ bí aguntan sí ààrin ìkookò. Ẹ má mú àpò owó lọ́wọ́, tabi àpò báárà. Ẹ má wọ bàtà. Bẹ́ẹ̀ ní kí ẹ má kí ẹnikẹ́ni ní ọ̀nà. Ilékílé tí ẹ bá wọ̀, ẹ kọ́kọ́ wí pé, ‘Alaafia fún ilé yìí.’ Bí ọmọ alaafia bá wà níbẹ̀, alaafia yín yóo máa wà níbẹ̀. Bí kò bá sí, alaafia yín yóo pada sọ́dọ̀ yín. Ninu ilé kan náà ni kí ẹ máa gbé. Ohun tí wọ́n bá gbé kalẹ̀ fun yín ni kí ẹ máa jẹ, kí ẹ sì máa mu. Owó iṣẹ́ alágbàṣe tọ́ sí i. Ẹ má máa lọ láti ilé dé ilé. Ìlúkílùú tí ẹ bá wọ̀, tí wọn bá gbà yín, ẹ máa jẹ ohun tí wọn bá gbé kalẹ̀ níwájú yín. Ẹ máa wo àwọn aláìsàn sàn. Kí ẹ sọ fún wọn pé, ‘Ìjọba Ọlọrun ti dé àrọ́wọ́tó yín.’ Ṣugbọn ìlúkílùú tí ẹ bá wọ̀ tí wọn kò bá gbà yín, ẹ jáde lọ sí títì ibẹ̀, kí ẹ sọ pé, ‘Erùpẹ̀ tí ó lẹ̀ mọ́ wa lẹ́sẹ̀ ninu ìlú yín, a gbọ̀n ọ́n kúrò kí ojú lè tì yín. Ṣugbọn kí ẹ mọ èyí pé ìjọba Ọlọrun wà ní àrọ́wọ́tó yín.’ Mo sọ fun yín pé yóo sàn fún Sodomu ní ọjọ́ ńlá náà jù fún ìlú náà lọ. “O gbé! Korasini. O gbé! Bẹtisaida. Nítorí bí ó bá jẹ́ pé ní Tire ati ní Sidoni ni a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe láàrin yín ni, wọn ìbá ti ronupiwada tipẹ́tipẹ́, wọn ìbá jókòó ninu eérú pẹlu aṣọ ọ̀fọ̀. Yóo sàn fún Tire ati fún Sidoni ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún yín lọ. Ìwọ Kapanaumu, o rò pé a óo gbé ọ ga dé ọ̀run ni? Rárá o! Ní ọ̀gbun jíjìn ni a óo sọ ọ́ sí! “Ẹni tí ó bá gbọ́ tiyín, ó gbọ́ tèmi. Ẹni tí ó bá kọ̀ yín èmi ni ó kọ̀. Ẹni tí ó bá sì wá kọ̀ mí, ó kọ ẹni tí ó fi iṣẹ́ rán mi.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejilelaadọrin pada dé pẹlu ayọ̀. Wọ́n ní, “Oluwa, àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá gbọ́ràn sí wa lẹ́nu ní orúkọ rẹ.” Ó bá sọ fún wọn pé, “Mo rí Satani tí ó ti ọ̀run já bọ́ bí ìràwọ̀. Mo fun yín ní àṣẹ láti tẹ ejò ati àkeekèé mọ́lẹ̀. Mo tún fun yín ní àṣẹ lórí gbogbo agbára ọ̀tá. Kò sí ohunkohun tí yóo pa yín lára. Ẹ má yọ̀ ní ti pé àwọn ẹ̀mí èṣù gbọ́ràn si yín lẹ́nu; ṣugbọn ẹ máa yọ̀ nítorí a ti kọ orúkọ yín sí ọ̀run.” Ní àkókò náà Jesu láyọ̀ ninu Ẹ̀mí Mímọ́. Ó ní, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Oluwa ọ̀run ati ayé, nítorí o ti pa nǹkan wọnyi mọ́ fún àwọn ọlọ́gbọ́n ati àwọn olóye; ṣugbọn o fi wọ́n han àwọn òpè. Bẹ́ẹ̀ ni, Baba, nítorí bí ó ti tọ́ ní ojú rẹ ni. “Baba mi ti fi ohun gbogbo lé mi lọ́wọ́. Kò sí ẹni tí ó mọ ẹni tí Ọmọ jẹ́, àfi Baba. Kò sí ẹni tí ó mọ ẹni tí Baba jẹ́, àfi Ọmọ; àtúnfi àwọn tí Ọmọ bá fẹ́ fi Baba hàn fún.” Jesu yipada sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ níkọ̀kọ̀, ó ní, “Ẹ ṣe oríire tí ojú yín rí àwọn ohun tí ẹ rí, nítorí mò ń sọ fun yín pé ọ̀pọ̀ àwọn wolii ati àwọn ọba ni wọ́n fẹ́ rí àwọn nǹkan tí ẹ rí, ṣugbọn tí wọn kò rí i; wọ́n fẹ́ gbọ́ ohun tí ẹ gbọ́ ṣugbọn wọn kò gbọ́ ọ.” Amòfin kan wá, ó fi ìbéèrè yìí wá Jesu lẹ́nu wò. Ó ní, “Olùkọ́ni, kí ni kí n ṣe kí n lè jogún ìyè ainipẹkun?” Jesu bi í pé, “Kí ni ó wà ní àkọsílẹ̀ ninu òfin? Báwo ni o ti túmọ̀ rẹ̀?” Ó dáhùn pé, “Kí ìwọ fẹ́ràn Oluwa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn rẹ, ati pẹlu gbogbo ẹ̀mí rẹ, ati pẹlu gbogbo agbára rẹ ati pẹlu gbogbo òye rẹ; sì fẹ́ràn ọmọnikeji rẹ bí ara rẹ.” Jesu sọ fún un pé, “O wí ire. Máa ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóo sì yè.” Ṣugbọn amòfin náà fẹ́ wẹ ara rẹ̀ mọ́. Ó wá bi Jesu pé, “Ta ni ọmọnikeji mi?” Jesu bá dá a lóhùn pé, “Ọkunrin kan ń ti Jerusalẹmu lọ sí Jẹriko, ni ó bá bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà. Wọ́n gba aṣọ lára rẹ̀, wọ́n lù ú, wọ́n bá fi í sílẹ̀ nígbà tí ó fẹ́rẹ̀ kú tán. Alufaa kan tí ó ń bọ̀ ṣe kòńgẹ́ rẹ̀ ní ọ̀nà, ṣugbọn nígbà tí ó rí i, ó gba òdìkejì kọjá lọ. Bákan náà ni ọmọ Lefi kan. Nígbà tí òun náà dé ibẹ̀, tí ó rí i, ó gba òdìkejì kọjá lọ. Ṣugbọn ará Samaria kan tí ó ń gba ọ̀nà yìí kọjá lọ dé ọ̀dọ̀ ọkunrin náà. Nígbà tí ó rí i, àánú ṣe é. Ó bá lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó fi òróró ati ọtí waini sí ojú ọgbẹ́ rẹ̀, ó sì fi aṣọ wé e. Ó gbé ọkunrin náà ka orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ tí ó gùn. Ó gbé e lọ sí ilé èrò níbi tí ó ti ṣe ìtọ́jú rẹ̀. Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, ó yọ owó fadaka meji jáde, ó fún olùtọ́jú ilé èrò, ó ní, ‘Ṣe ìtọ́jú ọkunrin yìí. Ohun tí o bá ná lé e lórí, n óo san án fún ọ nígbà tí mo bá pada dé.’ “Ninu àwọn mẹta yìí, ta ni o rò pé ó jẹ́ ọmọnikeji ẹni tí ó bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà?” Amòfin náà dáhùn pé, “Ẹni tí ó ṣàánú fún un ni.” Jesu sọ fún un pé, “Ìwọ náà lọ ṣe bẹ́ẹ̀ gan-an.” Bí wọ́n ti ń lọ ninu ìrìn àjò wọn, Jesu wọ inú abúlé kan. Obinrin kan tí ń jẹ́ Mata bá gbà á lálejò. Mata ní arabinrin kan tí ó ń jẹ́ Maria. Maria yìí jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ṣugbọn Mata kò rójú nítorí aájò tí ó ń ṣe nípa oúnjẹ. Ni Mata bá wá, ó ní, “Alàgbà, arabinrin mi fi èmi nìkan sílẹ̀ láti máa tọ́jú oúnjẹ, o sì dákẹ́ ò ń wò ó níran! Sọ fún un kí ó wá ràn mí lọ́wọ́.” Ṣugbọn Oluwa dá a lóhùn pé, “Mata! Mata! Ò ń ṣe aájò, o sì ń dààmú nípa ohun pupọ. Ṣugbọn ẹyọ nǹkankan ni ó jẹ́ koṣeemani. Maria ti yan ipò tí ó dára tí a kò ní gbà kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.” Nígbà kan, Jesu wà níbìkan, ó ń gbadura. Nígbà tí ó parí, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Oluwa, kọ́ wa bí a ti í gbadura gẹ́gẹ́ bí Johanu ti kọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.” Ó sọ fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ bá ń gbadura, ẹ máa wí pé, ‘Baba, ọ̀wọ̀ ni orúkọ rẹ. Kí ìjọba rẹ dé. Máa fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lojoojumọ. Dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, nítorí àwa náà ń dáríjì gbogbo ẹni tí ó bá jẹ wá ní gbèsè. Má ṣe fà wá sinu ìdánwò.’ ” Ó tún fi kún un fún wọn pé, “Bí ẹnìkan ninu yín bá ní ọ̀rẹ́ kan, tí ó wá lọ sọ́dọ̀ ọ̀rẹ́ yìí ní ọ̀gànjọ́ òru, tí ó sọ fún un pé, ‘Ọ̀rẹ́ mi, yá mi ní burẹdi mẹta, nítorí ọ̀rẹ́ mi kan ti ìrìn àjò dé bá mi, n kò sì ní oúnjẹ tí n óo fún un’; kí ọ̀rẹ́ náà wá ti inú ilé dáhùn pé, ‘Má yọ mí lẹ́nu. Mo ti ti ìlẹ̀kùn, àwọn ọmọ mi sì wà lórí ẹní pẹlu mi, n kò lè tún dìde kí n fún ọ ní nǹkankan mọ́.’ Mò ń sọ fun yín pé, bí kò tilẹ̀ fẹ́ dìde kí ó fún ọ nítorí o jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, ṣugbọn nítorí tí o kò tijú láti wá kan ìlẹ̀kùn mọ́ ọn lórí lóru, yóo dìde, yóo fún ọ ní ohun tí o nílò. “Bákan náà mo sọ fun yín, ẹ bèèrè, a óo fi fun yín; ẹ wá kiri, ẹ óo rí; ẹ kanlẹ̀kùn, a óo sì ṣí i fun yín. Nítorí gbogbo ẹni tí ó bá bèèrè ni yóo rí gbà; ẹni tí ó bá wá kiri yóo rí; ẹni tí ó bá sì kan ìlẹ̀kùn ni a óo ṣí i fún. Baba wo ninu yín ni ó jẹ́ fún ọmọ rẹ̀ ní ejò, nígbà tí ọmọ bá bèèrè ẹja? Tabi bí ó bá bèèrè ẹyin tí ó jẹ́ fún un ní àkeekèé? Nítorí náà bí ẹ̀yin tí ẹ burú báyìí bá mọ̀ bí a tií fún àwọn ọmọ yín ní ohun tí ó dára, mélòó-mélòó ni Baba yín ọ̀run yóo fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún àwọn tí ó bá bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” Ní ìgbà kan, Jesu ń lé ẹ̀mí èṣù kan tí ó yadi jáde. Nígbà tí ẹ̀mí Èṣù náà ti jáde tán ọkunrin odi náà sọ̀rọ̀, ẹnu wá ya àwọn eniyan. Ṣugbọn àwọn kan ninu wọn ń sọ pé, “Agbára Beelisebulu, olórí àwọn ẹ̀mí èṣù, ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.” Àwọn ẹlòmíràn ń dẹ ẹ́, wọ́n ń bèèrè àmì ọ̀run láti ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ṣugbọn Jesu mọ èrò wọn, ó sọ fún wọn pé, “Gbogbo ìjọba tí ó bá gbé ogun ti ara rẹ̀ yóo parun, ilé tí ó bá dìde sí ara rẹ̀ yóo tú ká. Bí Satani bá gbé ogun ti ara rẹ̀, báwo ni ìjọba rẹ̀ ṣe lè dúró? Nítorí ẹ̀ ń sọ pé agbára Beelisebulu ni mo fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Bí ó bá jẹ́ agbára Beelisebulu ni èmi fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, agbára wo ni àwọn ọmọ yín fi ń lé wọn jáde? Ní ti èrò yín yìí, àwọn ọmọ yín ni yóo ṣe onídàájọ́ yín. Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ ọwọ́ Ọlọrun ni mo fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, a jẹ́ pé ìjọba Ọlọrun ti dé ba yín. “Nígbà tí ọkunrin alágbára bá wà ní ihamọra, tí ó ń ṣọ́ ilé rẹ̀, kò sí ohun tí ó lè ṣe dúkìá rẹ̀. Ṣugbọn nígbà tí ẹni tí ó lágbára jù ú lọ bá dé, tí ó ṣẹgun rẹ̀, a gba ohun ìjà tí ó gbẹ́kẹ̀lé, a sì pín dúkìá rẹ̀ tí ó jí kó. “Ẹni tí kò bá sí lẹ́yìn mi, olúwarẹ̀ lòdì sí mi ni, ẹni tí kò bá ti bá mi kó nǹkan jọ, a jẹ́ pé títú ni ó ń tú wọn ká. “Nígbà tí ẹ̀mí èṣù bá jáde kúrò ninu ẹnìkan, á máa wá ilẹ̀ gbígbẹ kiri láti sinmi. Nígbà tí kò bá rí, á ní, ‘N óo tún pada sí ilé mi níbi tí mo ti jáde kúrò.’ Nígbà tí ó bá dé ibẹ̀, tí ó rí i pé a ti gbá a, a sì ti ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́, ẹ̀mí èṣù náà yóo bá lọ mú àwọn ẹ̀mí meje mìíràn wá tí wọ́n burú ju òun alára lọ, wọ́n óo bá wọ ibẹ̀ wọn óo máa gbébẹ̀. Ìgbẹ̀yìn ẹni náà á wá burú ju ti àkọ́kọ́ lọ.” Bí Jesu ti ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, obinrin kan láàrin àwọn eniyan fọhùn sókè pé, “Ẹni tí ó bí ọ, tí ó wò ọ́ dàgbà náà ṣe oríire lọpọlọpọ.” Ṣugbọn ó dáhùn pé, “Èyí tí ó jù ni pé àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun, tí wọ́n sì ń pa á mọ́ ṣe oríire.” Nígbà tí ọ̀pọ̀ eniyan péjọ yí i ká, ó bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, “Ìran burúkú ni ìran yìí; ó ń wá àmì. Kò sí àmì kan tí a óo fún un àfi àmì Jona. Nítorí bí Jona ti di àmì fún àwọn ará Ninefe, bẹ́ẹ̀ gan-an ni Ọmọ-Eniyan yóo jẹ́ àmì fún ìran yìí. Ayaba láti ilẹ̀ gúsù yóo dìde dúró ní ọjọ́ ìdájọ́ láti ko ìran yìí lójú, yóo sì dá wọn lẹ́bi. Nítorí ó wá láti òpin ilẹ̀ ayé láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n Solomoni, Ẹ wò ó! Ẹni tí ó ju Solomoni lọ wà níhìn-ín. Àwọn eniyan Ninefe yóo dìde dúró ní ọjọ́ ìdájọ́ láti ko ìran yìí lójú, wọn yóo sì dá wọn lẹ́bi. Nítorí wọ́n ronupiwada nígbà tí Jona waasu fún wọn. Ẹ wò ó! Ẹni tí ó ju Jona lọ wà níhìn-ín. “Kò sí ẹni tí ó jẹ́ tan fìtílà, tí ó jẹ́ fi pamọ́, tabi kí ó fi igbá bò ó. Ńṣe ni yóo gbé e ka orí ọ̀pá fìtílà kí àwọn tí ó bá ń wọlé lè ríran. Ojú ni ìmọ́lẹ̀ ara. Bí ojú rẹ bá ríran kedere, gbogbo ara rẹ yóo ní ìmọ́lẹ̀. Ṣugbọn bí ojú rẹ kò bá ríran, gbogbo ara rẹ ni yóo ṣókùnkùn. Nítorí náà kí ẹ ṣọ́ra kí ìmọ́lẹ̀ tí ó wà ninu yín má baà jẹ́ òkùnkùn. Bí gbogbo ara rẹ bá ní ìmọ́lẹ̀, tí kò sí ibìkan tí ó ṣókùnkùn, ńṣe ni yóo mọ́lẹ̀ bí ìgbà tí àtùpà bá tan ìmọ́lẹ̀ sí ọ lára.” Nígbà tí Jesu sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ tán, Farisi kan pè é pé kí ó wá jẹun ninu ilé rẹ̀. Ó bá wọlé, ó jókòó. Ẹnu ya Farisi náà nígbà tí ó rí i pé Jesu kò kọ́kọ́ wẹwọ́ kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí jẹun. Oluwa wá sọ fún un pé, “Ẹ̀yin Farisi a máa fọ òde kọ́ọ̀bù ati àwo oúnjẹ, ṣugbọn inú yín kún fún ìwà ipá ati nǹkan burúkú! Ẹ̀yin aṣiwèrè wọnyi! Mo ṣebí ẹni tí ó dá òde, òun náà ni ó dá inú. Ohun kan ni kí ẹ ṣe: ẹ fi àwọn ohun tí ó wà ninu kọ́ọ̀bù ati àwo ṣe ìtọrẹ àánú; bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, gbogbo nǹkan di mímọ́ fun yín. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin Farisi. Nítorí ẹ̀ ń ṣe ìdámẹ́wàá lórí ẹ̀fọ́ tẹ̀tẹ̀, gbúre ati oríṣìíríṣìí ewébẹ̀, nígbà tí ẹ kò ka ìdájọ́ òdodo ati ìfẹ́ Ọlọrun sí. Àwọn ohun tí ẹ kò kà sí wọnyi ni ó yẹ kí ẹ ṣe, láì gbàgbé àwọn nǹkan yòókù náà. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin Farisi. Nítorí ẹ fẹ́ràn ìjókòó iwájú ninu ilé ìpàdé. Ẹ tún fẹ́ràn kí eniyan máa ki yín láàrin ọjà. Ẹ gbé! Nítorí ẹ dàbí ibojì tí kò ní àmì, tí àwọn eniyan ń rìn lórí wọn, tí wọn kò mọ̀.” Ọ̀kan ninu àwọn amòfin sọ fún un pé, “Olùkọ́ni, nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ báyìí, ò ń fi àbùkù kan àwa náà!” Jesu dá a lóhùn pé, “Ẹ̀yin amòfin náà gbé! Nítorí ẹ̀ ń di ẹrù bàràkàtà-bàràkàtà lé eniyan lórí nígbà tí ẹ̀yin fúnra yín kò jẹ́ fi ọwọ́ yín kan ẹrù kan. Ẹ gbé! Nítorí ẹ̀ ń kọ́ ibojì àwọn wolii, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn baba yín ni wọ́n pa wọ́n. Ṣíṣe tí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ fi yín hàn bí ẹlẹ́rìí pé ẹ lóhùn sí ìwà àwọn baba yín: wọ́n pa àwọn wolii, ẹ̀yin wá ṣe ibojì sí ojú-oórì wọn. Ìdí nìyí tí ọgbọ́n Ọlọrun ṣe wí pé, ‘N óo rán àwọn wolii ati àwọn òjíṣẹ́ si yín, ẹ óo pa ninu wọn, ẹ óo ṣe inúnibíni sí àwọn mìíràn.’ Nítorí náà, ìran yìí ni yóo dáhùn fún ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn wolii tí a ti ta sílẹ̀ láti ìpìlẹ̀ ayé, ohun tí ó ṣẹ̀ lórí Abeli títí dé orí Sakaraya tí a pa láàrin ibi pẹpẹ ìrúbọ ati Ilé Ìrúbọ. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ìran yìí ni yóo dáhùn fún ẹ̀jẹ̀ gbogbo wọn. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin. Ẹ mú kọ́kọ́rọ́ ìmọ̀ lọ́wọ́, ẹ̀yin fúnra yín kò wọlé. Ẹ tún ń dá àwọn tí ó fẹ́ wọlé dúró!” Nígbà tí Jesu jáde kúrò ninu ilé, àwọn amòfin ati àwọn Farisi takò ó, wọ́n ń bi í léèrè ọ̀rọ̀ pupọ, wọ́n ń dẹ ẹ́ kí wọn lè ká ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu. Ní àkókò yìí, ogunlọ́gọ̀ eniyan péjọ; wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn fi ń tẹ ara wọn mọ́lẹ̀. Jesu kọ́ bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀ ná. Ó ní, “Ẹ ṣọ́ ara yín nípa ìwúkàrà àwọn Farisi, àwọn alágàbàgebè. Ṣugbọn kò sí ohun kan tí a fi aṣọ bò tí a kò ní ṣí aṣọ lórí rẹ̀. Kò sì sí ohun àṣírí tí eniyan kò ní mọ̀. Kí ẹ mọ̀ pé ohunkohun tí ẹ sọ ní ìkọ̀kọ̀, a óo gbọ́ nípa rẹ̀ ní gbangba. Ohun tí ẹ bá sọ ninu yàrá, lórí òrùlé ni a óo ti pariwo rẹ̀. “Mò ń sọ fun yín, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, pé kí ẹ má bẹ̀rù àwọn tí wọ́n lè pa ara, tí kò tún sí ohun tí wọ́n le ṣe mọ́ lẹ́yìn rẹ̀! N óo fi ẹni tí ẹ̀ bá bẹ̀rù hàn yín. Ẹ bẹ̀rù ẹni tí ó jẹ́ pé nígbà tí ó bá pa ara tán, ó ní àṣẹ láti tún sọ eniyan sinu ọ̀run àpáàdì. Mo sọ fun yín, ẹ bẹ̀rù olúwarẹ̀. “Mo ṣebí kọbọ meji ni wọ́n ń ta ológoṣẹ́ marun-un. Sibẹ kò sí ọ̀kan ninu wọn tí Ọlọrun fi ojú fò dá. Àní sẹ́, gbogbo irun orí yín ni ó níye. Ẹ má bẹ̀rù, ẹ níye lórí pupọ ju ológoṣẹ́ lọ. “Mo sọ fun yín, gbogbo ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú eniyan, Ọmọ-Eniyan yóo jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú àwọn angẹli Ọlọrun. Ṣugbọn ẹni tí ó bá sẹ́ mi níwájú eniyan ni a óo sẹ́ níwájú àwọn angẹli Ọlọrun. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ kan lòdì sí Ọmọ-Eniyan, a óo dáríjì í. Ṣugbọn ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ẹ̀mí Mímọ́, a kò ní dáríjì í. “Nígbà tí wọ́n bá mu yín lọ sinu ilé ìpàdé ati siwaju àwọn ìjòyè ati àwọn aláṣẹ, ẹ má ṣe dààmú nípa bí ẹ óo ti ṣe wí àwíjàre tabi pé kí ni ẹ óo sọ. Nítorí Ẹ̀mí Mímọ́ yóo kọ yín ní ohun tí ó yẹ kí ẹ sọ ní àkókò náà.” Ẹnìkan ninu àwọn eniyan sọ fún un pé, “Olùkọ́ni, sọ fún arakunrin mi kí ó fún mi ní ogún tí ó kàn mí.” Jesu dá a lóhùn pé, “Arakunrin, ta ni ó yàn mí ní onídàájọ́ tabi ẹni tí ń pín ogún kiri?” Jesu wá sọ fún àwọn eniyan pé, “Ẹ ṣọ́ra, ẹ ta kété sí ojúkòkòrò ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà, nítorí ọ̀pọ̀ dúkìá nìkan kọ́ níí sọni di eniyan.” Jesu bá pa òwe kan fún wọn. Ó ní, “Ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan wà tí ìkórè oko rẹ̀ pọ̀ pupọ. Ó wá ń rò ninu ọkàn rẹ̀ pé, ‘Kí ni ǹ bá ṣe o, nítorí n kò rí ibi kó ìkórè oko mi pamọ́ sí?’ Ó ní, ‘Mo mọ ohun tí n óo ṣe! Ńṣe ni n óo wó àwọn abà mi. N óo wá kọ́ àwọn ńláńlá mìíràn; níbẹ̀ ni n óo kó àgbàdo mi sí ati àwọn ìkórè yòókù. N óo wá sọ fún ọkàn mi pé: ọkàn mi, o ní ọ̀pọ̀ irè-oko tí ó wà ní ìpamọ́ fún ọdún pupọ. Ìdẹ̀ra dé. Máa jẹ, máa mu, máa gbádùn!’ Ṣugbọn Ọlọrun wí fún un pé, ‘Ìwọ aṣiwèrè yìí! Ní alẹ́ yìí ni a óo gba ẹ̀mí rẹ pada lọ́wọ́ rẹ. Ta ni yóo wá jogún gbogbo ohun tí o kó jọ wọnyi?’ “Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún ẹni tí ó to ìṣúra jọ fún ara rẹ̀, tí kò ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọrun.” Jesu bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Nítorí èyí ni mo ṣe sọ fun yín pé kí ẹ má máa páyà nípa ẹ̀mí yín, pé kí ni ẹ óo jẹ, tabi pé kí ni ẹ óo fi bora. Nítorí ẹ̀mí ṣe pataki ju oúnjẹ lọ, ara sì ṣe pataki ju aṣọ lọ. Ẹ ṣe akiyesi àwọn ẹyẹ; wọn kì í fúnrúgbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kórè. Wọn kò ní ilé tí wọn ń kó nǹkan pamọ́ sí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní abà. Sibẹ Ọlọrun ń bọ́ wọn. Mélòó-mélòó ni ẹ fi sàn ju àwọn ẹyẹ lọ. Ta ni ninu yín tí ó lè páyà títí dé ibi pé yóo fi ẹsẹ̀ bàtà kan kún gíga rẹ̀? Nítorí náà, bí ẹ kò bá lè ṣe ohun tí ó kéré jùlọ, kí ló dé tí ẹ fi ń páyà nípa àwọn nǹkan yòókù? Ẹ ṣe akiyesi àwọn òdòdó inú igbó bí wọ́n ti ń dàgbà. Wọn kì í ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í rànwú. Ṣugbọn mò ń sọ fun yín pé Solomoni pàápàá ninu ọlá rẹ̀ kò wọ aṣọ tí ó dára tó wọn. Bí Ọlọrun bá wọ koríko ìgbẹ́ láṣọ báyìí, koríko tí yóo wà lónìí, tí a óo fi dáná lọ́la, mélòó-mélòó ni yóo fi aṣọ wọ̀ yín, ẹ̀yin onigbagbọ kékeré yìí! “Nítorí náà, ẹ̀yin ẹ má máa páyà kiri nítorí ohun tí ẹ óo jẹ. (Nítorí pé irú nǹkan báwọ̀nyí ni àwọn alaigbagbọ ayé yìí ń dààmú kiri sí.) Baba yín sá mọ̀ pé ẹ nílò wọn. Ṣugbọn kí ẹ máa kọ́kọ́ wá ìjọba rẹ̀, gbogbo nǹkan wọnyi ni yóo fun yín pẹlu. “Ẹ má bẹ̀rù mọ́, agbo kékeré; nítorí dídùn inú Baba yín ni láti fun yín ní ìjọba rẹ̀. Ẹ ta àwọn ohun tí ẹ ní, kí ẹ fi ṣe ìtọrẹ-àánú. Ẹ dá àpò fún ara yín tí kò ní gbó laelae; ẹ to ìṣúra tí ó dájú jọ sí ọ̀run, níbi tí olè kò lè súnmọ́, tí kòkòrò kò sì lè ba nǹkan jẹ́. Nítorí níbi tí ìṣúra yín bá wà, níbẹ̀ ni ọkàn yín náà yóo wà. “Ẹ wà ní ìmúrasílẹ̀, kí ẹ di ara yín ní àmùrè, kí àtùpà yín wà ní títàn. Kí ẹ dàbí àwọn tí ó ń retí oluwa wọn láti pada ti ibi igbeyawo dé. Nígbà tí ó bá dé, tí ó bá kanlẹ̀kùn, lẹsẹkẹsẹ ni wọn yóo ṣí ìlẹ̀kùn fún un. Àwọn ẹrú tí oluwa wọn bá dé, tí ó bá wọn, tí wọn ń ṣọ́nà, ṣe oríire. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, yóo di ara rẹ̀ ní àmùrè, yóo fi wọ́n jókòó lórí tabili, yóo wá gbé oúnjẹ ka iwájú wọn. Bí ó bá dé ní ọ̀gànjọ́, tabi ní àkùkọ ìdájí, tí ó bá wọn bẹ́ẹ̀, wọ́n ṣe oríire. Kí ẹ mọ èyí pé bí ó bá jẹ́ pé baálé ilé mọ àkókò tí olè yóo dé, kò ní fi ilé rẹ̀ sílẹ̀ kí olè kó o. Ẹ̀yin náà, ẹ wà ní ìmúrasílẹ̀, nítorí ní àkókò tí ẹ kò nírètí ni Ọmọ-Eniyan yóo dé.” Peteru wá bi Jesu pé, “Oluwa, àwa ni o pa òwe yìí fún tabi fún gbogbo eniyan?” Oluwa sọ pé, “Ta ni olóòótọ́ ati ọlọ́gbọ́n ọmọ-ọ̀dọ̀, ẹni tí oluwa rẹ̀ fi ṣe olórí àwọn iranṣẹ ilé rẹ̀ pé kí ó máa fún wọn ní oúnjẹ lásìkò. Ọmọ-ọ̀dọ̀ náà ṣe oríire tí oluwa rẹ̀ bá bá a tí ó ń ṣe bí wọ́n ti rán an nígbà tí ó bá dé. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé oluwa rẹ̀ yóo fi ṣe ọ̀gá lórí gbogbo nǹkan tí ó ní. Ṣugbọn bí ọmọ-ọ̀dọ̀ náà bá rò ní ọkàn rẹ̀ pé, ‘Yóo pẹ́ kí oluwa mi tó dé,’ tí ó wá bẹ̀rẹ̀ sí lu àwọn iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, tí ó ń jẹ, tí ó ń mu, tí ó tún ń mutí yó, ní ọjọ́ tí ọmọ-ọ̀dọ̀ náà kò retí, ati ní àkókò tí kò rò tẹ́lẹ̀ ni oluwa rẹ̀ yóo dé, yóo kun ún wẹ́lẹwẹ̀lẹ, yóo sì fún un ní ìpín pẹlu àwọn alaiṣootọ. “Ọmọ-ọ̀dọ̀ tí ó bá mọ ohun tí oluwa rẹ̀ fẹ́, ṣugbọn tí kò múra sílẹ̀, tí kò sì ṣe ìfẹ́ oluwa rẹ̀ yóo jìyà pupọ. Ṣugbọn èyí tí kò bá mọ̀, tí ó bá tilẹ̀ ṣe ohun tí ó fi yẹ kí ó jìyà, ìyà díẹ̀ ni yóo jẹ. Nítorí ẹni tí a bá fún ní nǹkan pupọ, nǹkan pupọ ni a óo retí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ẹni tí a bá sì fi nǹkan pupọ ṣọ́, nǹkan pupọ ni a óo bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀. “Iná ni mo wá sọ sí ayé. Ìbá ti dùn tó bí ó bá bẹ̀rẹ̀ sí jó! Ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kan gbọdọ̀ ṣẹlẹ̀ sí mi. Ara mi kò lè balẹ̀ títí yóo fi kọjá. Ẹ má ṣe rò pé alaafia ni mo mú wá sí ayé. Bẹ́ẹ̀ kọ́, ará! Mò ń sọ fun yín, ìyapa ni mo mú wá. Láti ìgbà yìí, ẹni marun-un yóo wà ninu ilé kan, àwọn mẹta yóo lòdì sí àwọn meji; àwọn meji yóo lòdì sí àwọn mẹta. Baba yóo lòdì sí ọmọ, ọmọ yóo lòdì sí baba. Ìyá yóo lòdì sí ọmọ rẹ̀ obinrin, ọmọbinrin yóo lòdì sí ìyá rẹ̀. Ìyakọ yóo lòdì sí iyawo ilé, iyawo ilé yóo lòdì sì ìyakọ rẹ̀.” Jesu tún sọ fún àwọn eniyan pé, “Nígbà tí ẹ bá rí i tí òjò ṣú ní ìwọ̀ oòrùn, ẹ óo sọ pé, ‘Òjò yóo rọ̀.’ Bẹ́ẹ̀ ni yóo sì rí. Bí atẹ́gùn bá fẹ́ wá láti gúsù, ẹ máa ń sọ pé, ‘Ooru yóo mú,’ Bẹ́ẹ̀ ni yóo sì rí. Ẹ̀yin alágàbàgebè! Ẹ mọ àmì ilẹ̀ ati ti ojú sánmà, ṣugbọn ẹ kò mọ àmì àkókò yìí! “Kí ló dé tí ẹ̀yin fúnra yín kò fi lè mọ ohun tí ó tọ̀nà? Bí o bá ń bá ẹni tí ó pè ọ́ lẹ́jọ́ lọ sí kóòtù, gbìyànjú láti yanjú ọ̀rọ̀ náà pẹlu rẹ̀ bí ẹ ti ń lọ lọ́nà. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó lè fà ọ́ lé onídàájọ́ lọ́wọ́. Onídàájọ́ yóo bá fi ọ́ lé ọlọ́pàá lọ́wọ́, ni ọlọ́pàá yóo bá tì ọ́ mọ́lé. Mo fẹ́ kí o mọ̀ pé, o kò ní jáde kúrò níbẹ̀ títí o óo fi san gbogbo gbèsè tí o jẹ, láìku kọbọ!” Ní àkókò náà gan-an, àwọn kan sọ fún un nípa àwọn ará Galili kan tí Pilatu pa bí wọ́n ti ń rúbọ lọ́wọ́. Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ rò pé àwọn ará Galili wọnyi jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ju gbogbo ará Galili yòókù lọ ni, tí wọ́n fi jẹ irú ìyà yìí? Rárá o! Mò ń sọ fun yín pé bí ẹ kò bá ronupiwada, gbogbo yín ni ẹ óo ṣègbé bákan náà. Tabi àwọn mejidinlogun tí ilé-ìṣọ́ gíga ní Siloamu wólù, tí ó pa wọ́n, ṣé ẹ rò pé wọ́n burú ju gbogbo àwọn eniyan yòókù tí ó ń gbé Jerusalẹmu lọ ni? Rárá ó! Mo sọ fun yín pé bí ẹ kò bá ronupiwada, gbogbo yín ni ẹ óo ṣègbé bákan náà.” Ó wá pa òwe yìí fún wọn. Ó ní, “Ẹnìkan gbin igi ọ̀pọ̀tọ́ sinu ọgbà rẹ̀. Ó dé, ó ń wá èso lórí rẹ̀, ṣugbọn kò rí. Ó wá sọ fún olùtọ́jú ọgbà pé, ‘Ṣé o rí i! Ó di ọdún mẹta tí mo ti ń wá èso lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí tí n kò rí. Gé e lulẹ̀. Kí ló dé tí yóo kàn máa gbilẹ̀ lásán?’ Ṣugbọn olùtọ́jú ọgbà dá a lóhùn pé, ‘Alàgbà, fi í sílẹ̀ ní ọdún yìí, kí n walẹ̀ yí i ká, kí n bu ilẹ̀dú sí i. Bí ó bá so èso ní ọdún tí ń bọ̀, ó dára. Bí kò bá so èso, gé e.’ ” Jesu ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ ninu ilé ìpàdé kan ní Ọjọ́ Ìsinmi. Obinrin kan wà tí ó ní irú ẹ̀mí èṣù kan tí ó sọ ọ́ di aláìlera fún ọdún mejidinlogun. Ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ̀, kò lè nàró dáradára. Nígbà tí Jesu rí i, ó pè é, ó sọ fún un pé, “Obinrin yìí, a wò ọ́ sàn kúrò ninu àìlera rẹ.” Jesu bá gbé ọwọ́ mejeeji lé e. Lẹsẹkẹsẹ ni ẹ̀yìn rẹ̀ bá nà, ó bá ń fi ògo fún Ọlọrun. Ṣugbọn inú bí olórí ilé ìpàdé nítorí Jesu ṣe ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi. Ó bá sọ fún àwọn eniyan pé, “Ọjọ́ mẹfa wà tí a níláti fi ṣiṣẹ́. Ẹ wá fún ìwòsàn láàrin àwọn ọjọ́ mẹfa yìí. Ẹ má wá fún ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi mọ́!” Ṣugbọn Oluwa dá a lóhùn pé, “Ẹ̀yin alágàbàgebè! Èwo ninu yín ni kì í tú mààlúù tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ ní ibùjẹ ẹran kí ó lọ fún un ní omi ní Ọjọ́ Ìsinmi? Ẹ wá wo obinrin yìí, ọmọ Abrahamu, tí Satani ti dè fún ọdún mejidinlogun. Ṣé kò yẹ kí á tú u sílẹ̀ ninu ìdè yìí ní Ọjọ́ Ìsinmi?” Nígbà tí ó sọ̀rọ̀ báyìí, ojú ti gbogbo àwọn tí ó takò o. Ńṣe ni inú gbogbo àwọn eniyan dùn nítorí gbogbo ohun ìyanu tí ó ń ṣe. Nítorí náà Jesu sọ pé, “Kí ni à bá fi ìjọba Ọlọrun wé? Kí ni ǹ bá fi ṣe àkàwé rẹ̀? Ó dàbí ẹyọ wóró musitadi kan, tí ẹnìkan mú, tí ó gbìn sí oko rẹ̀. Nígbà tí ó bá dàgbà, ó di igi, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run wá ń ṣe ìtẹ́ wọn sí orí ẹ̀ka rẹ̀.” Ó tún sọ pé, “Kí ni ǹ bá fi ìjọba Ọlọrun wé? Ó dàbí ìwúkàrà tí obinrin kan mú, tí ó pò mọ́ òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun ńláńlá mẹta títí gbogbo rẹ̀ fi wú sókè.” Bí Jesu ti ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ láti ìlú dé ìlú ati láti abúlé dé abúlé, ó ń kọ́ àwọn eniyan bí ó ti ń lọ sí Jerusalẹmu. Ẹnìkan wá bi í pé, “Alàgbà, ǹjẹ́ àwọn eniyan tí yóo là kò ní kéré báyìí?” Jesu wá sọ fún àwọn eniyan pé, “Ẹ dù láti gba ẹnu ọ̀nà tí ó há wọlé, nítorí mò ń sọ fun yín pé ọpọlọpọ ni ó ń wá ọ̀nà láti wọlé ṣugbọn wọn kò lè wọlé. Nígbà tí baálé ilé bá ti dìde, tí ó bá ti ìlẹ̀kùn, ẹ óo wá dúró lóde, ẹ óo bẹ̀rẹ̀ sí kanlẹ̀kùn, ẹ óo wí pé, ‘Alàgbà, ṣílẹ̀kùn fún wa!’ Ṣugbọn yóo da yín lóhùn pé, ‘Èmi kò mọ̀ yín rí!’ Ẹ óo wá máa sọ pé, ‘A jẹ, a mu níwájú rẹ. O kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ ní ìgboro wa.’ Ṣugbọn yóo sọ fun yín pé, ‘Èmi kò mọ̀ yín rí. Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin oníṣẹ́ ibi.’ Ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà nígbà tí ẹ bá rí Abrahamu ati Isaaki ati Jakọbu ati gbogbo àwọn wolii ní ìjọba Ọlọrun, tí wọ́n wá tì yín mọ́ òde. Àwọn eniyan yóo wá láti ìlà oòrùn ati láti ìwọ̀ oòrùn, láti àríwá ati láti gúsù, wọn yóo jókòó níbi àsè ní ìjọba Ọlọrun. Àwọn èrò ẹ̀yìn yóo di ará iwájú; àwọn ará iwájú yóo di èrò ẹ̀yìn.” Ní àkókò náà, àwọn Farisi kan wá sọ́dọ̀ Jesu, wọ́n sọ fún un pé, “Kúrò níhìn-ín nítorí Hẹrọdu fẹ́ pa ọ́.” Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ lọ sọ fún ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ yẹn pé, ‘Mò ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, mo tún ń ṣe ìwòsàn lónìí ati lọ́la. Ní ọ̀tunla n óo parí iṣẹ́ mi.’ Mo níláti kúrò kí n máa bá iṣẹ́ mi lọ lónìí, lọ́la ati lọ́tùn-unla, nítorí bí wolii kan yóo bá kú, ní Jerusalẹmu ni yóo ti kú. “Jerusalẹmu! Jerusalẹmu! Ìwọ tí ò ń pa àwọn wolii, tí ò ń sọ òkúta lu àwọn tí a ti rán sí ọ, nígbà mélòó ni mo ti fẹ́ kó àwọn ọmọ rẹ jọ, bí adìẹ tií kó àwọn ọmọ rẹ̀ sí abẹ́ ìyẹ́ rẹ̀, ṣugbọn ẹ kò gbà fún mi! Ẹ wò ó! Ọlọrun ti fi ìlú yín sílẹ̀ fun yín! Ṣugbọn mo wí fun yín pé ẹ kò ní rí mi títí di ìgbà tí ẹ óo wí pé, ‘Alábùkún ni ẹni tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Oluwa.’ ” Ní Ọjọ́ Ìsinmi kan, Jesu lọ jẹun ní ilé ọ̀kan ninu àwọn olóyè láàrin àwọn Farisi. Wọ́n bá ń ṣọ́ ọ. Ọkunrin kan wà níwájú rẹ̀ níbẹ̀ tí gbogbo ara rẹ̀ wú bòmù-bòmù. Jesu bi àwọn amòfin ati àwọn Farisi tí ó wà níbẹ̀ pé, “Ṣé ó dára láti ṣe ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi, tabi kò dára?” Wọ́n bá dákẹ́. Jesu bá mú ọkunrin náà, ó wò ó sàn, ó bá ní kí ó máa lọ. Ó wá bi wọ́n pé, “Ta ni ninu yín tí ọmọ rẹ̀, tabi mààlúù rẹ̀ yóo já sinu kànga ní Ọjọ́ Ìsinmi, tí kò ní fà á yọ lẹsẹkẹsẹ?” Wọn kò sì lè dá a lóhùn. Nígbà tí Jesu ṣe akiyesi bí àwọn tí a pè sí ibi àsè ti ń yan ipò ọlá, ó wá pa òwe kan fún wọn. Ó ní, “Nígbà tí ẹnìkan bá pè ọ́ sí ibi iyawo, má ṣe lọ jókòó ní ipò ọlá. Bóyá ẹni tí ó pè ọ́ tún pe ẹlòmíràn tí ó lọ́lá jù ọ́ lọ. Ẹni tí ó pè ọ́ yóo wá tọ̀ ọ́ wá, yóo sọ fún ọ pé, ‘Fi ààyè fún ọkunrin yìí,’ Ìwọ yóo wá fi ìtìjú bẹ̀rẹ̀ sí máa wá ààyè lẹ́yìn. Tí wọn bá pè ọ́, lọ jókòó lẹ́yìn, kí ẹni tí ó pè ọ́ lè wá sọ fún ọ pé, ‘Ọ̀rẹ́ mi súnmọ́ iwájú.’ Nígbà náà ìwọ yóo ní iyì lójú gbogbo àwọn tí ó wà níbi àsè. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a óo rẹ̀ sílẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óo gbé ga.” Ó wá sọ fún ẹni tí ó pè é fún oúnjẹ pé, “Nígbà tí o bá se àsè, ìbáà jẹ́ lọ́sàn-án tabi lálẹ́, má ṣe pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tabi àwọn arakunrin rẹ tabi àwọn ẹbí rẹ tabi àwọn aládùúgbò rẹ tí wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀. Bí o bá pè wọ́n, àwọn náà yóo pè ọ́ wá jẹun níjọ́ mìíràn, wọn yóo sì san oore tí o ṣe wọ́n pada fún ọ. Ṣugbọn bí o bá se àsè, pe àwọn aláìní, àwọn aláàbọ̀ ara, àwọn afọ́jú. Èyí ni yóo fún ọ láyọ̀, nítorí wọn kò lè san án pada fún ọ. Ṣugbọn Ọlọrun yóo san án pada fún ọ nígbà tí àwọn olódodo bá jí dìde kúrò ninu òkú.” Nígbà tí ẹnìkan ninu àwọn tí ó wà níbi àsè gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó sọ fún Jesu pé, “Ẹni tí ó bá jẹun ní ìjọba ọ̀run ṣe oríire!” Jesu sọ fún un pé, “Ọkunrin kan se àsè ńlá kan; ó pe ọ̀pọ̀ eniyan sibẹ. Nígbà tí àkókò ati jẹun tó, ó rán iranṣẹ rẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn tí ó ti pè láti sọ fún wọn pé, ‘Ó yá o! A ti ṣetán!’ Ni gbogbo wọn patapata láìku ẹnìkan bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwáwí. Ekinni sọ fún un pé, ‘Mo ra ilẹ̀ kan, mo sì níláti lọ wò ó. Mo tọrọ àforíjì, yọ̀ǹda mi.’ Ẹnìkejì ní, ‘Mo ra mààlúù fún ẹ̀rọ-ìroko. Mò ń lọ dán an wò, dákun, yọ̀ǹda mi.’ Ẹnìkẹta ní, ‘Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé iyawo ni, nítorí náà n kò lè wá.’ “Iranṣẹ náà bá pada lọ jíṣẹ́ fún oluwa rẹ̀. Inú wá bí baálé ilé náà. Ó sọ fún iranṣẹ rẹ̀ pé, ‘Tètè lọ sí gbogbo títì ati ọ̀nà ẹ̀bùrú ìlú, kí o lọ kó àwọn aláìní, àwọn aláàbọ̀ ara, àwọn afọ́jú, ati àwọn arọ wá síhìn-ín.’ Nígbà tí iranṣẹ náà ti ṣe bẹ́ẹ̀ tán, ó ní, ‘Alàgbà, a ti ṣe bí o ti pàṣẹ, sibẹ àyè tún kù.’ Oluwa iranṣẹ náà sọ fún un pé, ‘Lọ sí ọ̀nà oko, kí o bẹ àwọn ẹni tí o bá rí, kí wọ́n wọlé wá, kí inú ilé mi baà kún. Nítorí kò sí ọ̀kan ninu àwọn eniyan wọ̀n-ọn-nì tí a ti kọ́kọ́ pè tí yóo tọ́ wò ninu àsè mi!’ ” Ọ̀pọ̀ àwọn eniyan péjọ pọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó bá yíjú pada sí wọn, ó ní, “Bí ẹnìkan bá fẹ́ wá sọ́dọ̀ mi, bí kò bá kórìíra baba rẹ̀ ati ìyá rẹ̀, ati iyawo rẹ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati ẹ̀gbọ́n, ati àbúrò rẹ̀, lọkunrin ati lobinrin, tí ó fi mọ́ ẹ̀mí òun pàápàá, kò lè jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi. Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbé agbelebu rẹ̀, kí ó máa tọ̀ mí lẹ́yìn kò lè jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi. “Nítorí ta ni ninu yín tí yóo fẹ́ kọ́ ilé ńlá kan, tí kò ní kọ́kọ́ jókòó kí ó ṣírò iye tí yóo ná òun, kí ó mọ̀ bí òun bá ní ohun tí òun yóo fi parí rẹ̀? Kí ó má wá jẹ́ pé yóo fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ tán, kò ní lè parí rẹ̀ mọ́. Gbogbo àwọn tí ó bá rí i yóo wá bẹ̀rẹ̀ sí fi ṣe yẹ̀yẹ́. Wọn yóo máa wí pé, ‘Ọkunrin yìí bẹ̀rẹ̀ ilé, kò lè parí rẹ̀!’ “Tabi ọba wo ni yóo lọ ko ọba mìíràn lójú ogun tí kò ní kọ́kọ́ jókòó kí ó gba ìmọ̀ràn bí òun yóo bá lè ko ẹni tí ó ní ọ̀kẹ́ kan ọmọ-ogun lójú? Bí kò bá ní lè kò ó lójú, kí ọ̀tá rẹ̀ tó dé ìtòsí, yóo tètè rán ikọ̀ sí i pé òun túúbá. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ẹnikẹ́ni ninu yín tí kò bá kọ gbogbo ohun tí ó ní sílẹ̀, kò lè jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi. “Iyọ̀ dára. Ṣugbọn bí iyọ̀ bá di òbu, báwo ni a ti ṣe lè mú kí ó tún dùn? Kó wúlò fún oko tabi fún ààtàn mọ́ àfi kí á dà á sóde. Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́!” Gbogbo àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àwọn Farisi ati àwọn amòfin wá ń kùn; wọ́n ń sọ pé, “Eléyìí ń kó àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ mọ́ra, ó tún ń bá wọn jẹun.” Jesu bá pa òwe yìí fún wọn. Ó ní: “Bí ọkunrin kan bá ní ọgọrun-un aguntan tí ọ̀kan sọnù ninu wọn, ṣé kò ní fi mọkandinlọgọrun-un yòókù sílẹ̀ ní pápá, kí ó wá èyí tí ó sọnù lọ títí yóo fi rí i? Nígbà tí ó bá wá rí i, yóo gbé e kọ́ èjìká rẹ̀ pẹlu ayọ̀. Nígbà tí ó bá dé ilé, yóo pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ati àwọn aládùúgbò rẹ̀ jọ, yóo wí fún wọn pé, ‘Ẹ bá mi yọ̀, nítorí mo ti rí aguntan mi tí ó sọnù.’ Mo sọ fun yín, bẹ́ẹ̀ gan-an ni, ayọ̀ tí yóo wà ní ọ̀run nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronupiwada ju ti ìtorí àwọn olódodo mọkandinlọgọrun-un tí kò nílò ìrònúpìwàdà lọ. “Tabi, kí obinrin kan ní naira mẹ́wàá, bí ó ba sọ naira kan nù, ṣé kò ní tan iná, kí ó gbálẹ̀, kí ó fẹ̀sọ̀ wá a títí yóo fi rí i? Nígbà tí ó bá rí i, yóo pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ati àwọn aládùúgbò rẹ̀ jọ, yóo sọ fún wọn pé, ‘Ẹ bá mi yọ̀, nítorí mo ti rí owó tí mo sọnù.’ Mo sọ fun yín, bẹ́ẹ̀ gan-an ni àwọn angẹli Ọlọrun yóo máa yọ̀ nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronupiwada.” Jesu ní, “Ọkunrin kan ní ọmọ meji. Èyí àbúrò sọ fún baba rẹ̀ pé, ‘Baba, fún mi ní ogún tèmi tí ó tọ́ sí mi.’ Ni baba bá pín ogún fún àwọn ọmọ mejeeji. Kò pẹ́ lẹ́yìn rẹ̀ tí àbúrò yìí fi kó gbogbo ohun ìní rẹ̀, ó bá lọ sí ìlú òkèèrè, ó sá fi ìwà wọ̀bìà ná gbogbo ohun ìní rẹ̀ pátá ní ìnákúnàá. Nígbà tí ó ná gbogbo ohun ìní rẹ̀ tán, ìyàn wá mú pupọ ní ìlú náà, ebi sì bẹ̀rẹ̀ sí pa á. Ni ó bá lọ ń gbé ọ̀dọ̀ ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ ibẹ̀. Ọmọ-ìbílẹ̀ ìlú yìí ba rán an lọ sí oko rẹ̀ láti máa ṣe ìtọ́jú ẹlẹ́dẹ̀. Ìbá dùn mọ́ ọn láti máa jẹ oúnjẹ tí àwọn ẹlẹ́dẹ̀ ń jẹ, ṣugbọn ẹnikẹ́ni kì í fún un ní ohunkohun. Nígbà tí ojú rẹ̀ wálẹ̀, ó ní, ‘Àwọn alágbàṣe baba mi tí wọn ń jẹ oúnjẹ ní àjẹṣẹ́kù kò níye. Èmi wá jókòó níhìn-ín, ebi ń pa mí kú lọ! N óo dìde, n óo tọ baba mi lọ. N óo wí fún un pé, “Baba, mo ti ṣẹ Ọlọrun, mo sì ti ṣẹ ìwọ náà. N kò yẹ ní ẹni tí à bá máa pè ní ọmọ rẹ mọ́. Fi mí ṣe ọ̀kan ninu àwọn alágbàṣe rẹ.” ’ Ó bá dìde, ó lọ sí ọ̀dọ̀ baba rẹ̀. “Bí ó ti ń bọ̀ ní òkèèrè ni baba rẹ̀ ti rí i. Àánú ṣe é, ó yára, ó dì mọ́ ọn lọ́rùn, ó bá fẹnu kò ó ní ẹnu. Ọmọ náà sọ fún un pé, ‘Baba, mo ti ṣẹ Ọlọrun, mo sì ti ṣẹ ìwọ náà.’ Ṣugbọn baba náà sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, ‘Ẹ tètè mú aṣọ tí ó dára jùlọ wá, kí ẹ fi wọ̀ ọ́. Ẹ fi òrùka sí i lọ́wọ́, ẹ fún un ní bàtà kí ó wọ̀. Ẹ wá lọ mú mààlúù tí ó sanra wá, kí ẹ pa á, kí ẹ jẹ́ kí á máa ṣe àríyá. Nítorí ọmọ mi yìí ti kú, ṣugbọn ó tún wà láàyè; ó ti sọnù, ṣugbọn a ti rí i.’ Ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àríyá. “Ní gbogbo àkókò yìí, èyí ẹ̀gbọ́n wà ní oko. Bí ó ti ń bọ̀ tí ó ń súnmọ́ etílé, ó gbọ́ ìlù ati ijó. Ó pe ọmọde kan, ó wádìí ohun tí ń ṣẹlẹ̀. Ọmọ yìí bá sọ fún un pé, ‘Àbúrò rẹ dé, baba rẹ sì pa mààlúù tí ó sanra, ó se àsè nítorí tí àbúrò rẹ pada dé ní alaafia.’ Inú bí èyí ẹ̀gbọ́n, ó bá kọ̀, kò wọlé. Ni baba rẹ̀ bá jáde lọ láti lọ bẹ̀ ẹ́. Ṣugbọn ó sọ fún baba rẹ̀ pé, ‘Wo ati ọdún tí mo ti ń sìn ọ́, n kò dá àṣẹ rẹ kọjá rí; sibẹ o kò fún mi ni ọmọ ewúrẹ́ kan kí n fi ṣe àríyá pẹlu àwọn ọ̀rẹ́ mi rí. Ṣugbọn nígbà tí ọmọ rẹ yìí dé, àpà ara rẹ̀, tí ó ti run ogún rẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn aṣẹ́wó, o wá pa mààlúù tí ó sanra fún un.’ Baba rẹ̀ dá a lóhùn pé, ‘Ọmọ mi, ìwọ wà lọ́dọ̀ mi nígbà gbogbo, gbogbo ohun tí mo ní, tìrẹ ni. Ó yẹ kí á ṣe àríyá, kí á sì máa yọ̀, nítorí àbúrò rẹ yìí ti kú, ó sì tún yè, ó ti sọnù, a sì tún rí i.’ ” Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan wà tí ó ní ọmọ-ọ̀dọ̀ kan. Wọ́n fi ẹ̀sùn kan ọmọ-ọ̀dọ̀ yìí pé ó ń fi nǹkan ọ̀gá rẹ̀ ṣòfò. Ọ̀gá rẹ̀ bá pè é, ó sọ fún un pé, ‘Irú ìròyìn wo ni mò ń gbọ́ nípa rẹ yìí? Ṣírò iṣẹ́ rẹ bí ọmọ-ọ̀dọ̀, nítorí n óo dá ọ dúró lẹ́nu iṣẹ́.’ Ọmọ-ọ̀dọ̀ náà wá rò ninu ara rẹ̀ pé, ‘Kí ni n óo ṣe o, nítorí ọ̀gá mi yóo dá mi dúró lẹ́nu iṣẹ́. Èmi nìyí, n kò lè roko. Ojú sì ń tì mí láti máa ṣagbe. Mo mọ ohun tí n óo ṣe, kí àwọn eniyan lè gbà mí sinu ilé wọn nígbà tí wọ́n bá gba iṣẹ́ lọ́wọ́ mi.’ “Ó bá pe ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn tí ó jẹ ọ̀gá rẹ̀ ní gbèsè. Ó bi ekinni pé, ‘Èló ni o jẹ ọ̀gá mi?’ Òun bá dáhùn pé, ‘Ọgọrun-un garawa epo.’ Ó sọ fún un pé, ‘Gba ìwé àkọsílẹ̀ rẹ, tètè jókòó, kọ aadọta.’ Ó bi ekeji pé, ‘Ìwọ ńkọ́? Èló ni o jẹ?’ Ó ní, ‘Ẹgbẹrun òṣùnwọ̀n àgbàdo.’ Ó sọ fún un pé, ‘Gba ìwé àkọsílẹ̀ rẹ, kọ ẹgbẹrin.’ “Ọ̀gá ọmọ-ọ̀dọ̀ ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ náà yìn ín nítorí pé ó gbọ́n. Nítorí àwọn ọmọ ayé yìí mọ ọ̀nà ọgbọ́n tí wọ́n fi ń bá ara wọn lò ju àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀ lọ. “Ní tèmi, mò ń sọ fun yín, fún anfaani ara yín, ẹ fi ọrọ̀ ayé yìí wá ọ̀rẹ́ fún ara yín, tí ó fi jẹ́ pé nígbà tí owó kò bá sí mọ́, kí wọn lè gbà yín sí inú ibùgbé tí yóo wà títí lae. Ẹni tí ó bá ṣe olóòótọ́ ninu nǹkan kékeré yóo ṣe olóòótọ́ ninu nǹkan ńlá. Nítorí náà bí ẹ kò bá ṣe é gbẹ́kẹ̀lé nípa nǹkan owó ti ayé yìí, ta ni yóo fi dúkìá tòótọ́ sí ìkáwọ́ yín? Bí ẹ kò bá ṣe é gbẹ́kẹ̀lé nípa ohun tí ó jẹ́ ti ẹlòmíràn, ta ni yóo fun yín ní ohun tí ó jẹ́ ti ẹ̀yin fúnra yín? “Kò sí ọmọ-ọ̀dọ̀ kan tí ó lè sin oluwa meji. Nítorí ọ̀kan ni yóo ṣe: ninu kí ó kórìíra ọ̀kan, kí ó fẹ́ràn ekeji, tabi kí ó fara mọ́ ọ̀kan, kí ó má sì ka ekeji sí. Ẹ kò lè sin Ọlọrun, kí ẹ tún sin owó.” Nígbà tí àwọn Farisi tí wọ́n fẹ́ràn owó gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí, ńṣe ni wọ́n ń yínmú sí i. Ó wá sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni ẹ̀ ń dá ara yín láre lójú eniyan, ṣugbọn Ọlọrun mọ ọkàn yín. Ohun tí eniyan ń gbé gẹ̀gẹ̀, ohun ẹ̀gbin ni lójú Ọlọrun. “Ìwé òfin Mose ati ìwé àwọn wolii ni ó wà fún ìlànà títí di àkókò Johanu. Láti ìgbà náà ni a ti ń waasu ìyìn rere ti ìjọba Ọlọrun. Pẹlu ipá sì ni olukuluku fi ń wọ̀ ọ́. Ó rọrùn kí ọ̀run ati ayé kọjá ju pé kí kínńkínní ninu òfin kí ó má ṣẹ lọ. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ iyawo rẹ̀ sílẹ̀ tí ó gbé iyawo mìíràn ṣe àgbèrè. Bí ẹnìkan bá sì gbé obinrin tí a ti kọ̀ sílẹ̀ ní iyawo òun náà ṣe àgbèrè. “Ọkunrin kán wà tí ó lówó. Aṣọ àlàárì ati àwọn aṣọ olówó iyebíye mìíràn ni ó máa ń wọ̀. Oúnjẹ àdídùn ni ó máa ń jẹ, lojoojumọ ni ó máa ń se àsè. Talaka kan wà tí ó ń jẹ́ Lasaru, tíí máa ń jókòó lẹ́nu ọ̀nà ilé ọlọ́rọ̀ yìí. Gbogbo ara Lasaru jẹ́ kìkì egbò. Inú rẹ̀ ìbá dùn láti máa jẹ ẹ̀rúnrún tí ó ń bọ́ sílẹ̀ láti orí tabili olówó yìí. Pẹlu bẹ́ẹ̀ náà, ajá a máa wá lá egbò ara rẹ̀. “Nígbà tí ó yá, talaka yìí kú, àwọn angẹli bá gbé e lọ sọ́dọ̀ Abrahamu. Olówó náà kú, a sì sin ín. Ní ipò òkú ni ó rí ara rẹ̀, tí ó ń joró. Ó wá rí Abrahamu ní òkèèrè pẹlu Lasaru ní ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ó bá pè é, ó ní, ‘Abrahamu, Baba, ṣàánú mi. Rán Lasaru kí ó ti ìka rẹ̀ bọ omi, kí ó wá kán an sí mi láhọ́n, nítorí mò ń jẹ ìrora ninu iná yìí.’ “Ṣugbọn Abrahamu dá a lóhùn pé, ‘Ọmọ, ranti pé nígbà tí o wà láyé, kìkì ohun rere ni o gbà, nígbà tí ó jẹ́ pé nǹkan burúkú ni Lasaru gbà. Nisinsinyii, ìdẹ̀ra ti dé bá Lasaru nígbà tí ìwọ ń jẹ̀rora. Ati pé ọ̀gbun ńlá kan wà láàrin àwa ati ẹ̀yin, tí ó fi jẹ́ pé àwọn tí ó bá fẹ́ kọjá sí ọ̀dọ̀ yín kò ní lè kọjá; bákan náà àwọn tí ó bá fẹ́ ti ọ̀hún kọjá wá sí ọ̀dọ̀ wa kò ní lè kọjá.’ Olówó náà wá sọ pé, ‘Baba, bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, mo bẹ̀ ọ́, rán Lasaru lọ sí ilé baba mi. Arakunrin marun-un ni mo ní; kí ó lọ kìlọ̀ fún wọn kí àwọn náà má baà wá sí ibi oró yìí.’ “Ṣugbọn Abrahamu dá a lóhùn pé, ‘Wọ́n ní ìwé Mose ati ìwé àwọn wolii. Kí wọ́n fetí sí wọn.’ Ṣugbọn ọlọ́rọ̀ náà ní, ‘Ó tì, Abrahamu, Baba! Bí ẹnìkan bá jí dìde ninu òkú, tí ó lọ sọ́dọ̀ wọn, wọn yóo ronupiwada.’ Ṣugbọn Abrahamu sọ fún un pé, ‘Bí wọn kò bá fetí sí ohun tí Mose ati àwọn wolii kọ, bí ẹni tí ó ti kú bá tilẹ̀ jí dìde tí ó lọ bá wọn, kò ní lè yí wọn lọ́kàn pada.’ ” Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “A kò lè ṣàì rí ohun ìkọsẹ̀, ṣugbọn ẹni tí ó ti ọwọ́ rẹ̀ ṣẹ̀ gbé! Ó sàn fún un kí á so ọlọ mọ́ ọn lọ́rùn, kí á jù ú sinu òkun jù pé kí ó mú ohun ìkọsẹ̀ bá ọ̀kan ninu àwọn kékeré wọnyi. Ẹ ṣọ́ra yín! “Bí arakunrin rẹ bá ṣẹ̀ ọ́, bá a wí; bí ó bá ronupiwada, dáríjì í. Bí ó bá ṣẹ̀ ọ́ ní ẹẹmeje ní ọjọ́ kan, tí ó yipada sí ọ lẹẹmeje, tí ó bẹ̀ ọ́ pé, ‘Jọ̀ọ́ má bínú,’ dáríjì í.” Àwọn aposteli sọ fún Oluwa pé, “Bù sí igbagbọ wa!” Oluwa sọ fún wọn pé, “Bí ẹ bá ní igbagbọ tí ó kéré bíi wóró musitadi tí ó kéré jùlọ, bí ẹ bá wí fún igi sikamore yìí pé, ‘Hú kúrò níbí tigbòǹgbò- tigbòǹgbò, kí o lọ hù ninu òkun!’ Yóo ṣe bí ẹ ti wí. “Bí ẹnìkan ninu yín bá ní iranṣẹ kan tí ó lọ roko tabi tí ó lọ tọ́jú àwọn aguntan, tí ó bá wọlé dé láti inú oko, ǹjẹ́ ohun tí yóo sọ fún un ni pé kí ó tètè wá jókòó kí ó jẹun? Àbí yóo sọ fún iranṣẹ náà pé, ‘Tọ́jú ohun tí n óo jẹ. Ṣe gírí kí o gbé oúnjẹ fún mi. Nígbà tí mo bá jẹ tán, tí mo mu tán, kí o wá jẹ tìrẹ.’ Ǹjẹ́ ó jẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ọmọ-ọ̀dọ̀ nítorí pé ó ṣe ohun tí ó níláti ṣe? Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kí ẹ ṣe. Nígbà tí ẹ bá ti ṣe ohun gbogbo tí a pa láṣẹ fun yín tán, kí ẹ sọ pé, ‘Ọmọ-ọ̀dọ̀ ni a jẹ́. Ohun tí a ṣe kì í ṣe ọ̀rọ̀ ọpẹ́. Ohun tí ó yẹ kí á ṣe ni a ti ṣe.’ ” Bí Jesu ti ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ sí Jerusalẹmu, ó ń gba ààrin Samaria ati Galili kọjá. Bí ó tí ń wọ abúlé kan lọ, àwọn ọkunrin adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá kan pàdé rẹ̀. Wọ́n dúró lókèèrè, wọ́n kígbe pé, “Ọ̀gá, Jesu, ṣàánú wa.” Nígbà tí ó rí wọn, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ fi ara yín hàn alufaa.” Bí wọ́n ti ń lọ, ara wọn bá dá. Nígbà tí ọ̀kan ninu wọn rí i pé ara òun ti dá, ó pada, ó ń fi ìyìn fún Ọlọrun pẹlu ohùn gíga. Ó bá dojúbolẹ̀ níwájú Jesu, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Ará Samaria ni. Jesu bèèrè pé, “Ṣebí àwọn mẹ́wàá ni mo mú lára dá. Àwọn mẹsan-an yòókù dà? Kò wá sí ẹni tí yóo pada wá dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, àfi àlejò yìí?” Jesu bá sọ fún un pé, “Dìde, máa lọ. Igbagbọ rẹ ni ó mú ọ lára dá.” Àwọn Farisi bi Jesu nípa ìgbà tí ìjọba Ọlọrun yóo dé. Ó dá wọn lóhùn pé, “Dídé ìjọba Ọlọrun kò ní àmì tí a óo máa fẹjú kí á tó ri pé ó dé tabi kò dé. Kì í ṣe ohun tí àwọn eniyan yóo máa sọ pé, ‘Ó wà níhìn-ín’ tabi ‘Ó wà lọ́hùn-ún.’ Nítorí ìjọba Ọlọrun wà láàrin yín.” Ó wá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Ọjọ́ ń bọ̀ tí ẹ óo fẹ́ rí ọ̀kan ninu ọjọ́ dídé Ọmọ-Eniyan, ṣugbọn ẹ kò ní rí i. Wọn yóo máa sọ pé, ‘Wò ó níhìn-ín’ tabi, ‘Wò ó lọ́hùn-ún’. Ẹ má lọ, ẹ má máa sáré tẹ̀lé wọn kiri. Nítorí bí mànàmáná tíí kọ yànràn, tíí sìí tan ìmọ́lẹ̀ láti òkè délẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Ọmọ-Eniyan yóo rí ní ọjọ́ tí ó bá dé. Ṣugbọn dandan ni pé kí ó kọ́kọ́ jìyà pupọ, kí ìran yìí sì kẹ̀yìn sí i. Àní bí ó ti rí ní àkókò Noa, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí nígbà tí Ọmọ-Eniyan bá dé. Nítorí ní àkókò Noa, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń gbeyawo, wọ́n ń fi ọmọ fọ́kọ, títí di ọjọ́ tí Noa fi wọ inú ọkọ̀, ìkún-omi bá dé, ó bá pa gbogbo wọn rẹ́. Bákan náà ni ó rí ní àkókò ti Lọti. Wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń rà, wọ́n ń tà, wọ́n ń fúnrúgbìn, wọ́n ń kọ́lé, títí di ọjọ́ tí Lọti fi jáde kúrò ní Sodomu, tí Ọlọrun fi rọ̀jò iná ati òkúta gbígbóná lé wọn lórí, tí ó pa gbogbo wọn rẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí ní ọjọ́ tí Ọmọ-Eniyan bá yọ dé. “Ní ọjọ́ náà, bí ẹnìkan bá wà lórí ilé, tí àwọn nǹkan rẹ̀ wà ninu ilé, kí ó má sọ̀kalẹ̀ lọ kó o. Bákan náà ni ẹni tí ó bá wà lóko kò gbọdọ̀ pada sílé. Ẹ ranti iyawo Lọti Ẹni tí ó bá ń wá ọ̀nà láti gba ẹ̀mí rẹ̀ là, yóo pàdánù rẹ̀. Ẹni tí ó bá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀, yóo gbà á là. Mo sọ fun yín, ní ọjọ́ náà, eniyan meji yóo sùn lórí ibùsùn kan, a óo mú ọ̀kan, a óo fi ekeji sílẹ̀. Àwọn obinrin meji yóo máa lọ ògì, a óo mú ọ̀kan, a óo fi ekeji sílẹ̀. [ Àwọn ẹni meji yóo wà ní oko, a óo mú ọ̀kan, a óo fi ekeji sílẹ̀.”] Wọ́n bi í pé, “Níbo ni, Oluwa?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Níbi tí òkú ẹran bá wà, níbẹ̀ ni àwọn igún ń péjọ sí.” Jesu pa òwe kan fún wọn láti kọ́ wọn pé eniyan gbọdọ̀ máa gbadura nígbà gbogbo, láì ṣàárẹ̀. Ó ní, “Adájọ́ kan wà ní ìlú kan tí kò bẹ̀rù Ọlọrun, tí kò sì ka ẹnikẹ́ni sí. Opó kan wà ninu ìlú náà tíí máa lọ sí ọ̀dọ̀ adájọ́ yìí tíí máa bẹ̀ ẹ́ pé, ‘Ṣe ẹ̀tọ́ fún mi nípa ọ̀rọ̀ tí ó wà láàrin èmi ati ọ̀tá mi.’ Ọjọ́ ń gorí ọjọ́, sibẹ adájọ́ yìí kò fẹ́ ṣe nǹkankan nípa ọ̀rọ̀ náà. Nígbà tí ó pẹ́, ó wá bá ara rẹ̀ sọ pé, ‘Bí n kò tilẹ̀ bìkítà fún ẹnikẹ́ni, ìbáà ṣe Ọlọrun tabi eniyan, ṣugbọn nítorí opó yìí ń yọ mí lẹ́nu, n óo ṣe ẹ̀tọ́ fún un, kí ó má baà fi wahala rẹ̀ da mí lágara!’ ” Oluwa wá sọ pé, “Ẹ kò gbọ́ ohun tí adájọ́ alaiṣootọ yìí wí! Ǹjẹ́ Ọlọrun kò ní ṣe ẹ̀tọ́ nípa àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ tí wọn ń pè é lọ́sàn-án ati lóru? Ǹjẹ́ kò ní tètè dá wọn lóhùn? Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé yóo ṣe ẹ̀tọ́ fún wọn kíákíá. Ǹjẹ́ nígbà tí Ọmọ-Eniyan bá dé, yóo bá igbagbọ ní ayé mọ́?” Ó wá pa òwe yìí fún àwọn tí wọ́n gbójú lé ara wọn bí olódodo, tí wọn ń kẹ́gàn gbogbo àwọn eniyan yòókù. Ó ní, “Àwọn ọkunrin meji kan gòkè lọ sí Tẹmpili wọ́n lọ gbadura. Ọ̀kan jẹ́ Farisi, ekeji jẹ́ agbowó-odè. “Èyí Farisi dá dúró, ó bẹ̀rẹ̀ sí gbadura pé, ‘Ọlọrun, mo dúpẹ́ pé ń kò dàbí àwọn yòókù, àwọn oníwọ̀ra, alaiṣootọ, alágbèrè. N kò tilẹ̀ dàbí agbowó-odè yìí. Ẹẹmeji ni mò ń gbààwẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Mò ń dá ìdámẹ́wàá gbogbo nǹkan tí mo bá gbà.’ “Ṣugbọn èyí agbowó-odè dúró ní òkèèrè. Kò tilẹ̀ gbé ojú sókè. Ó bá ń lu ara rẹ̀ láyà (bí àmì ìdárò), ó ní, ‘Ọlọrun ṣàánú mi, èmi ẹlẹ́ṣẹ̀.’ Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé agbowó-odè yìí lọ sí ilé rẹ̀ pẹlu ọkàn ìdáláre ju èyí Farisi lọ. Nítorí ẹni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a óo rẹ̀ sílẹ̀; ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óo gbé ga.” Àwọn eniyan ń gbé àwọn ọmọ-ọwọ́ wá, pé kí ó lè fi ọwọ́ kàn wọ́n. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn tí wọ́n gbé wọn wá wí. Ṣugbọn Jesu pè wọ́n, ó ní, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọde wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má dá wọn dúró, nítorí irú wọn ni ìjọba Ọlọrun. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ẹni tí kò bá gba ìjọba Ọlọrun bí ọmọde, kò ní wọ inú rẹ̀.” Ìjòyè kan bi Jesu léèrè pé, “Olùkọ́ni rere, kí ni kí n ṣe kí n lè jogún ìyè ainipẹkun?” Jesu sọ fún un pé, “Ìdí rẹ̀ tí o fi ń pè mí ní ẹni rere? Kò sí ẹni rere kan àfi Ọlọrun nìkan ṣoṣo. Ṣé o mọ òfin wọnyi: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè; ìwọ kò gbọdọ̀ paniyan; ìwọ kò gbọdọ̀ jalè; ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké; bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ.’ ” Ìjòyè náà dáhùn pé, “Gbogbo òfin wọnyi ni mo ti ń pamọ́ láti ìgbà tí mo ti wà ní ọdọmọkunrin.” Nígbà tí Jesu gbọ́, ó sọ fún un pé, “Nǹkankan ló kù ọ́ kù. Lọ ta gbogbo ohun tí o ní, kí o pín owó rẹ̀ fún àwọn talaka, ìwọ yóo wá ní ìṣúra ní ọ̀run. Kí o máa wá tọ̀ mí lẹ́yìn.” Nígbà tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, inú rẹ̀ bàjẹ́, nítorí ó ní ọrọ̀ pupọ. Nígbà tí Jesu rí bí inú rẹ̀ ti bàjẹ́, ó ní, “Yóo ṣòro fún àwọn olówó láti wọ ìjọba Ọlọrun. Ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ kọjá, jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọrun.” Àwọn tí ó gbọ́ ní, “Ta wá ni a óo gbà là?” Ó dáhùn pé, “Ohun tí kò ṣeéṣe fún eniyan, ó ṣeéṣe fún Ọlọrun.” Peteru sọ fún un pé, “Wò ó ná! Àwa ti fi ohun gbogbo tí a ní sílẹ̀, a sì ti ń tẹ̀lé ọ.” Ó bá sọ fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé kò sí ẹni tí ó fi ilé, iyawo, arakunrin, òbí tabi ọmọ sílẹ̀, nítorí ti ìjọba Ọlọrun, tí kò ní rí ìlọ́po-ìlọ́po gbà ní ayé yìí, yóo sì ní ìyè ainipẹkun ní ayé tí ń bọ̀.” Ó mú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila lọ sápá kan, ó sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí Jerusalẹmu tí à ń gòkè lọ yìí, gbogbo ohun tí àwọn wolii kọ nípa Ọmọ-Eniyan ni yóo ṣẹ. Nítorí a óo fi í lé àwọn tí kì í ṣe Juu lọ́wọ́. Wọn óo fi ṣe ẹ̀sín, wọn óo fi àbùkù kàn án, wọn óo tutọ́ sí i lára. Nígbà tí wọ́n bá nà án tán, wọn óo sì pa á. Ṣugbọn ní ọjọ́ kẹta, yóo jí dìde.” Ṣugbọn ohun tí ó sọ kò yé wọn. Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà sápamọ́ fún wọn. Wọn kò mọ ohun tí ó ń sọ. Nígbà tí Jesu súnmọ́ etí ìlú Jẹriko, afọ́jú kan wà lẹ́bàá ọ̀nà, ó jókòó, ó ń ṣagbe. Nígbà tí ó gbọ́ tí ọ̀pọ̀ eniyan ń kọjá lọ, ó wádìí ohun tí ó dé. Wọ́n sọ fún un pé, “Jesu ará Nasarẹti ní ń kọjá.” Ni alágbe náà bá pariwo pé, “Jesu, ọmọ Dafidi, ṣàánú mi!” Àwọn tí ó ń kọjá lọ ń bá a wí pé kí ó panu mọ́. Ṣugbọn ńṣe ni ó túbọ̀ ń kígbe pé, “Ọmọ Dafidi, ṣàánú mi.” Jesu bá dúró, ó ní kí wọ́n lọ fà á lọ́wọ́ wá sọ́dọ̀ òun. Nígbà tí ó dé, Jesu bi í pé, “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe fún ọ?” Ó dáhùn pé, “Alàgbà, mo fẹ́ tún ríran ni!” Jesu sọ fún un pé, “Ǹjẹ́, ríran. Igbagbọ rẹ mú ọ lára dá.” Lójú kan náà ó sì tún ríran, ó bá ń tẹ̀lé Jesu, ó ń yin Ọlọrun lógo. Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan rí i, wọ́n fi ìyìn fún Ọlọrun. Nígbà tí Jesu dé Jẹriko, ó ń la ìlú náà kọjá. Ọkunrin kan wà tí ó ń jẹ́ Sakiu. Òun ni olórí agbowó-odè níbẹ̀. Ó sì lówó. Ó fẹ́ rí Jesu kí ó mọ ẹni tí í ṣe. Ṣugbọn kò lè rí i nítorí ọ̀pọ̀ eniyan ati pé eniyan kúkúrú ni. Ó bá sáré lọ siwaju, ó gun igi sikamore kan kí ó lè rí i, nítorí ọ̀nà ibẹ̀ ni Jesu yóo gbà kọjá. Nígbà tí Jesu dé ọ̀gangan ibẹ̀, ó gbé ojú sókè, ó sọ fún un pé, “Sakiu, tètè sọ̀kalẹ̀, nítorí ọ̀dọ̀ rẹ ni mo gbọdọ̀ dé sí lónìí.” Ni Sakiu bá sọ̀kalẹ̀, ó sì fi ayọ̀ gbà á lálejò. Nígbà tí àwọn eniyan rí i, gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Jesu, wọ́n ní, “Lọ́dọ̀ ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ó lọ wọ̀ sí!” Sakiu bá dìde dúró, ó sọ fún Oluwa pé, “N óo pín ààbọ̀ ohun tí mo ní fún àwọn talaka. Bí mo bá sì ti fi ọ̀nà èrú gba ohunkohun lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, mo ṣetán láti dá a pada ní ìlọ́po mẹrin.” Jesu bá dá a lóhùn pé, “Lónìí yìí ni ìgbàlà wọ inú ilé yìí, nítorí ọmọ Abrahamu ni Sakiu náà. Nítoí Ọmọ-Eniyan dé láti wá àwọn tí wọ́n sọnù kiri, ati láti gbà wọ́n là.” Bí wọ́n ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọnyi, ó tún fi òwe kan bá wọn sọ̀rọ̀, nítorí ó súnmọ́ Jerusalẹmu, àwọn eniyan sí rò pé ó tó àkókò tí ìjọba Ọlọrun yóo farahàn. Nítorí náà ó sọ fún wọn pé, “Ọkunrin ìjòyè pataki kan lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, wọ́n fẹ́ fi jọba níbẹ̀ kí ó sì pada wálé lẹ́yìn náà Ó bá pe àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ mẹ́wàá, ó fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní owó wúrà kọ̀ọ̀kan. Ó ní, ‘Ẹ máa lọ fi ṣòwò kí n tó dé.’ Ṣugbọn àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ ibẹ̀ kórìíra rẹ̀. Wọ́n bá rán ikọ̀ ṣiwaju rẹ̀ láti lọ sọ pé àwọn kò fẹ́ kí ọkunrin yìí jọba lórí àwọn! “Nígbà tí ọkunrin yìí jọba tán, tí ó pada dé, ó bá ranṣẹ pe àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí ó ti fún lówó, kí ó baà mọ èrè tí wọ́n ti jẹ. Ekinni bá dé, ó ní, ‘Alàgbà, mo ti fi owó wúrà kan tí o fún mi pa owó wúrà mẹ́wàá.’ Oluwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘O ṣeun, ọmọ-ọ̀dọ̀ rere. O ti ṣe olóòótọ́ ninu ohun kékeré. Mo fi ọ́ ṣe aláṣẹ lórí ìlú mẹ́wàá.’ Ekeji dé, ó ní, ‘Alàgbà, mo ti fi owó wúrà rẹ pa owó wúrà marun-un.’ Oluwa rẹ̀ wí fún òun náà pé, ‘Mo fi ọ́ ṣe aláṣẹ lórí ìlú marun-un.’ “Ẹkẹta dé, ó ní, ‘Alàgbà, owó wúrà rẹ nìyí, aṣọ ni mo fi dì í, mo sì fi pamọ́, nítorí mo bẹ̀rù rẹ. Nítorí òǹrorò eniyan ni ọ́. Níbi tí o kò fi nǹkan sí ni o máa ń wá a sí; níbi tí o kò fúnrúgbìn sí ni o ti máa ń kórè.’ Oluwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ gan-an ni n óo fi ṣe ìdájọ́ rẹ, ìwọ ọmọ-ọ̀dọ̀ burúkú yìí. O mọ̀ pé níbi tí n kò fi nǹkan sí ni mo máa ń wá a sí, ati pé níbi tí n kò fúnrúgbìn sí ni mo ti máa ń kórè. Kí ni kò jẹ́ kí o lọ fi owó mi pamọ́ sí banki, tí ó fi jẹ́ pé bí mo ti dé yìí, ǹ bá gbà á pẹlu èlé?’ “Ó bá sọ fún àwọn tí ó dúró níbẹ̀ pé, ‘Ẹ gba owó wúrà náà ní ọwọ́ rẹ̀, kí ẹ fún ẹni tí ó ní owó wúrà mẹ́wàá.’ Wọ́n bá dá a lóhùn pé, ‘Alàgbà, ṣebí òun ti ní owó wúrà mẹ́wàá!’ Ó wá sọ fún wọn pé, ‘Gbogbo ẹni tí ó bá ní ni a óo tún fún sí i. Ọwọ́ ẹni tí kò sì ní, ni a óo ti gba ìba díẹ̀ tí ó ní! Ní ti àwọn ọ̀tá mi wọnyi, àwọn tí kò fẹ́ kí n jọba, ẹ mú wọn wá síhìn-ín, kí ẹ pa wọ́n lójú mi!’ ” Nígbà tí Jesu sọ̀rọ̀ yìí tán ó tẹ̀síwájú, ó gòkè lọ sí Jerusalẹmu. Nígbà tí ó súnmọ́ ẹ̀bá Bẹtifage ati Bẹtani, ní apá òkè tí à ń pè ní Òkè Olifi, ó rán meji ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí abúlé tí ó wà ní ọ̀kánkán yìí. Nígbà tí ẹ bá wọ ibẹ̀, ẹ óo rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí wọ́n so mọ́lẹ̀, tí ẹnikẹ́ni kò gùn rí. Ẹ tú u, kí ẹ fà á wá. Bí ẹnikẹ́ni bá bi yín pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ń tú u?’ Kí ẹ sọ fún un pé, ‘Oluwa nílò rẹ̀ ni.’ ” Àwọn tí ó rán bá lọ, wọ́n rí ohun gbogbo bí ó ti sọ fún wọn. Nígbà tí wọn ń tú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, àwọn oluwa rẹ̀ bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń tú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́?” Wọ́n sọ fún wọn pé, “Oluwa nílò rẹ̀ ni.” Wọ́n bá fà á lọ sọ́dọ̀ Jesu. Wọ́n tẹ́ ẹ̀wù wọn sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, wọ́n bá gbé Jesu gùn ún. Bí ó ti ń lọ, wọ́n ń tẹ́ ẹ̀wù wọn sọ́nà. Nígbà tí ó súnmọ́ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Olifi, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fi ayọ̀ kígbe sókè, wọ́n ń yin Ọlọrun nítorí gbogbo ohun ńlá tí wọ́n ti rí. Wọ́n ń wí pé, “Aláásìkí ni ẹni tí ó ń bọ̀ bí ọba ní orúkọ Oluwa. Alaafia ní ọ̀run! Ògo ní òkè ọ̀run!” Àwọn kan tí wọ́n jẹ́ Farisi tí wọ́n wà láàrin àwọn eniyan sọ fún un pé, “Olùkọ́ni, bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ wí.” Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Mò ń sọ fun yín pé, bí àwọn wọnyi bá dákẹ́, àwọn òkúta yóo kígbe sókè.” Nígbà tí wọ́n súnmọ́ etí ìlú, ó wo ìlú náà, ó bá bú sẹ́kún lórí rẹ̀. Ó ní, “Ìbá ti dára tó lónìí, bí o bá mọ̀ lónìí ohun tí ó jẹ́ ọ̀nà alaafia rẹ! Ṣugbọn ó pamọ́ fún ọ. Nítorí ọjọ́ ń bọ̀ tí àwọn ọ̀tá rẹ yóo gbógun tì ọ́, wọn óo yí ọ ká, wọn yóo há ọ mọ́ yípo. Wọn yóo wó ọ lulẹ̀, wọn yóo sì pa àwọn eniyan tí ó wà ninu rẹ. Wọn kò ní fi òkúta kan sílẹ̀ lórí ekeji ninu rẹ, nítorí o kò fura nígbà tí Ọlọrun wá bẹ̀ ọ́ wò!” Nígbà tí Jesu wọ inú Tẹmpili, ó bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn tí ń tajà jáde. Ó sọ fún wọn pè, “Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Ilé adura ni ilé mi,’ ṣugbọn ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibi tí àwọn ọlọ́ṣà ń sápamọ́ sí!” Ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu Tẹmpili lojoojumọ. Àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin, pẹlu àtìlẹ́yìn àwọn eniyan pataki-pataki ní ìlú, ń wá ọ̀nà láti pa á, ṣugbọn wọn kò rí ọ̀nà, nítorí gbogbo eniyan ń fi ìtara gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ní ọjọ́ kan, bí Jesu ti ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ ninu Tẹmpili, tí ó ń waasu ìyìn rere fún wọn, àwọn olórí alufaa, àwọn amòfin, ati àwọn àgbà wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Wọ́n bi í pé, “Sọ fún wa irú àṣẹ tí o fi ń ṣe àwọn nǹkan wọnyi; ta ni ó sì fún ọ ní àṣẹ yìí?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Èmi náà yóo bi yín ní ọ̀rọ̀ kan, ẹ dá mi lóhùn. Ìrìbọmi tí Johanu ń ṣe, láti ọ̀run wá ni, tabi láti ọ̀dọ̀ eniyan?” Wọ́n ń bá ara wọn sọ pé, “Bí a bá sọ pé, ‘Láti ọ̀run ni,’ yóo bi wá pé, ‘Kí ló dé tí ẹ kò fi gbà á gbọ́?’ Bí a bá sọ pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ eniyan ni,’ gbogbo àwọn eniyan yóo sọ wá ní òkúta pa, nítorí wọ́n gbà dájú pé wolii ni Johanu.” Wọ́n bá dá a lóhùn pé, “A kò mọ ibi tí ó ti wá.” Jesu bá sọ fún wọn pé, “Èmi náà kò ní sọ irú àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọnyi fún yín.” Ó wá pa òwe yìí fún àwọn eniyan. Ó ní, “Ọkunrin kan gbin àjàrà sinu ọgbà kan, ó gba àwọn alágbàro sibẹ, ó bá lọ sí ìrìn àjò. Ó pẹ́ níbi tí ó lọ. Nígbà tí ó yá, ó rán ẹrú rẹ̀ kan sí àwọn alágbàro náà. Ṣugbọn àwọn alágbàro yìí lù ú, wọ́n bá dá a pada ní ọwọ́ òfo. Ọkunrin yìí tún rán ẹrú mìíràn. Àwọn alágbàro yìí tún lù ú, wọ́n fi àbùkù kàn án, wọ́n bá tún dá òun náà pada ní ọwọ́ òfo. Ọkunrin yìí tún rán ẹnìkẹta. Wọ́n tilẹ̀ ṣe òun léṣe ni, ní tirẹ̀, wọ́n bá lé e jáde. Ẹni tí ó ni ọgbà yìí wá rò ninu ara rẹ̀ pé, ‘Kí ni n óo ṣe o? N óo rán àyànfẹ́ ọmọ mi, bóyá wọn yóo bọlá fún un.’ Ṣugbọn nígbà tí àwọn alágbàro yìí rí i, wọ́n bà ara wọn sọ pé, ‘Àrólé rẹ̀ nìyí. Ẹ jẹ́ kí á pa á, kí ogún rẹ̀ lè di tiwa.’ Ni wọ́n bá mú un jáde kúrò ninu ọgbà náà, wọ́n bá pa á. “Kí ni ẹni tí ó ni ọgbà náà yóo wá ṣe? Yóo pa àwọn alágbàro wọnyi, yóo sì gbé ọgbà rẹ̀ fún àwọn mìíràn láti tọ́jú.” Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n ní “Ọlọrun má jẹ́!” Jesu bá wò wọ́n lójú, ó ní, “Ǹjẹ́ kí ni ìtumọ̀ àkọsílẹ̀ yìí, ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀, òun ni ó di òkúta pataki ní igun ilé.’ Bí ẹnikẹ́ni bá ṣubú lu òkúta yìí, olúwarẹ̀ yóo fọ́ yángá-yángá, bí òkúta yìí bá sì bọ́ lu ẹnikẹ́ni, rírẹ́ ni yóo rẹ́ olúwarẹ̀ pẹ́tẹ́pẹ́tẹ́.” Àwọn akọ̀wé ati àwọn olórí alufaa gbèrò láti mú un ní wakati náà, nítorí wọ́n mọ̀ pé àwọn ni ó pa òwe yìí mọ́; ṣugbọn wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣọ́ ọ. Wọ́n rán àwọn amí kí wọ́n ṣe bí eniyan rere, kí wọ́n lè ká ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu, kí wọn wá fi lé gomina lọ́wọ́, kí gomina dá sẹ̀ría fún un. Wọ́n bi í pé, “Olùkọ́ni, a mọ̀ pé tààrà ni ò ń sọ̀rọ̀, tí o sì ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́. O kì í wo ojú eniyan kí o tó sọ̀rọ̀. Ṣugbọn pẹlu òtítọ́ ni ò ń kọ́ eniyan ní ọ̀nà Ọlọrun. Ṣé ó tọ́ fún wa láti san owó-orí fún Kesari, àbí kò tọ́?” Ṣugbọn ó ti mọ ẹ̀tàn wọn. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ fi owó fadaka kan hàn mí.” Ó bá bi wọ́n léèrè pé, “Àwòrán ati àkọlé ta ni ti ara rẹ̀ yìí?” Wọ́n ní, “Ti Kesari ni.” Ó bá wí fún wọn pé, “Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ fi ohun tí ó bá jẹ́ ti Kesari fún Kesari, kí ẹ sì fi ohun tí ó bá jẹ́ ti Ọlọrun fún Ọlọrun.” Wọn kò lè mú ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu lójú gbogbo eniyan. Ìdáhùn rẹ̀ yà wọ́n lẹ́nu, wọ́n bá dákẹ́. Àwọn kan ninu àwọn Sadusi bá lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. (Àwọn Sadusi ni wọn kò gbà pé òkú kan a tún máa jinde.) Wọ́n bi í pé, “Olùkọ́ni, Mose pàṣẹ fún wa pé bí eniyan bá ní iyawo, bí ó bá kú láìní ọmọ, kí àbúrò rẹ̀ ṣú iyawo rẹ̀ lópó, kí ó ní ọmọ lórúkọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò meje kan wà. Ekinni gbé iyawo, ó kú láìní ọmọ. Bẹ́ẹ̀ náà ni ekeji. Ẹkẹta náà ṣú u lópó. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn mejeeje ṣe, wọ́n kú láì ní ọmọ. Ní ìgbẹ̀yìn-gbẹ́yín, obinrin náà alára wá kú. Ní ọjọ́ ajinde, ti ta ni obinrin náà yóo jẹ́, nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn mejeeje ló ti fi ṣe aya?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àwọn eniyan ayé yìí ni wọ́n ń gbeyawo, tí wọn ń fi ọmọ fọ́kọ. Ṣugbọn àwọn tí a kà yẹ fún ayé tí ó ń bọ̀, nígbà tí àwọn òkú bá jinde, kò ní máa gbeyawo, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní máa fọmọ fọ́kọ. Nítorí wọn kò lè kú mọ́, nítorí bákan náà ni wọ́n rí pẹlu àwọn angẹli. Ọmọ Ọlọrun ni wọ́n, nítorí pé wọ́n jẹ́ ọmọ ajinde. Ó dájú pé a jí àwọn òkú dìde nítorí ohun tí Mose kọ ninu ìtàn ìgbẹ́ tí ń jóná, nígbà tí ó sọ pé, ‘Oluwa Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun ti Jakọbu.’ Ọlọrun kì í ṣe Ọlọrun àwọn òkú, ti àwọn alààyè ni; nítorí pé gbogbo wọn ni ó wà láàyè fún Ọlọrun.” Àwọn kan ninu àwọn amòfin dá a lóhùn pé, “Olùkọ́ni, o wí ire!” Láti ìgbà náà kò tún sí ẹni tí ó láyà láti bi í ní nǹkankan mọ́. Jesu bi wọ́n léèrè pé, “Báwo ni wọ́n ṣe ń pe Mesaya ní ọmọ Dafidi? Nítorí Dafidi sọ ninu ìwé Orin Dafidi pé, ‘Oluwa wí fún oluwa mi pé: Jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún mi títí n óo fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.’ Nígbà tí Dafidi pè é ní Oluwa, báwo ni ó ti ṣe tún jẹ́ ọmọ rẹ̀?” Ní etí gbogbo àwọn eniyan, Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ ṣọ́ra lọ́dọ̀ àwọn amòfin tí wọ́n fẹ́ máa wọ agbádá ńlá. Wọ́n tún gbádùn kí eniyan máa kí wọn ní ààrin ọjà. Wọ́n fẹ́ràn láti jókòó níwájú ninu ilé ìpàdé ati láti jókòó ní ipò ọlá níbi àsè. Wọn a máa jẹ ilé àwọn opó run. Wọ́n a máa gba adura gígùn láti ṣe àṣehàn. Wọn yóo gba ìdájọ́ líle.” Bí Jesu ti gbé ojú sókè ó rí àwọn ọlọ́rọ̀ bí wọ́n ti ń dá owó ọrẹ wọn sinu àpótí ìṣúra. Ó wá rí talaka opó kan, tí ó fi kọbọ meji sibẹ. Ó ní, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, owó ọrẹ talaka opó yìí ju ti gbogbo àwọn yòókù lọ. Nítorí gbogbo àwọn yòókù mú ọrẹ wá ninu ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n ní; ṣugbọn òun tí ó jẹ́ aláìní, ó mú gbogbo ohun tí ó fi ẹ̀mí tẹ̀ wá.” Àwọn kan ń sọ̀rọ̀ nípa Tẹmpili, wọ́n ń sọ nípa àwọn òkúta dáradára tí wọ́n fi ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ ati ọrẹ tí wọ́n mú wá fún Ọlọrun. Jesu bá dáhùn pé, “Ẹ rí gbogbo nǹkan wọnyi, ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí kò ní sí òkúta kan lórí ekeji tí a kò ní wó lulẹ̀.” Wọ́n bi í pé, “Olùkọ́ni, nígbà wo ni gbogbo nǹkan wọnyi yóo ṣẹ. Kí ni yóo sì jẹ́ àmì nígbà tí wọn yóo bá fi ṣẹ?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ṣọ́ra kí á má ṣe tàn yín jẹ. Nítorí ọ̀pọ̀ yóo wá ní orúkọ mi, tí wọn yóo wí pé, ‘Èmi ni Mesaya’ ati pé, ‘Àkókò náà súnmọ́ tòsí.’ Ẹ má tẹ̀lé wọn. Nígbà tí ẹ bá gbúròó ogun ati ìrúkèrúdò, ẹ má jẹ́ kí ó dẹ́rùbà yín. Nítorí dandan ni kí nǹkan wọnyi kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀. Ṣugbọn òpin kò níí tíì dé.” Ó tún fi kún un fún wọn pé “Orílẹ̀-èdè kan yóo máa gbógun ti ekeji, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba kan yóo sì máa gbógun ti ekeji. Ilẹ̀ yóo mì tìtì. Ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn yóo wà ní ibi gbogbo. Ohun ẹ̀rù ati àwọn àmì ńlá yóo hàn lójú ọ̀run. Kí gbogbo èyí tó ṣẹlẹ̀, wọn yóo dojú kọ yín, wọn yóo ṣe inúnibíni si yín. Wọn yóo fà yín lọ sí inú ilé ìpàdé ati sinu ẹ̀wọ̀n. Wọn yóo fà yín lọ siwaju àwọn ọba ati àwọn gomina nítorí orúkọ mi. Anfaani ni èyí yóo jẹ́ fun yín láti jẹ́rìí. Nítorí náà, ẹ má ronú tẹ́lẹ̀ ohun tí ẹ óo sọ láti dáàbò bo ara yín, nítorí èmi fúnra mi ni n óo fi ọ̀rọ̀ si yín lẹ́nu, n óo sì fun yín ní ọgbọ́n tí ó fi jẹ́ pé ẹnikẹ́ni ninu gbogbo àwọn tí ó lòdì si yín kò ní lè kò yín lójú, tabi kí wọ́n rí ohun wí si yín. Àwọn òbí yín, ati àwọn arakunrin yín, àwọn ẹbí yín, ati àwọn ọ̀rẹ́ yín, yóo kọ̀ yín, wọn yóo sì pa òmíràn ninu yín. Gbogbo eniyan ni yóo kórìíra yín nítorí orúkọ mi. Ṣugbọn irun orí yín kankan kò ní ṣègbé. Ẹ óo gba ọkàn yín là nípa ìdúróṣinṣin yín. “Nígbà tí ẹ bá rí i tí ogun yí ìlú Jerusalẹmu ká, kí ẹ mọ̀ pé àkókò tí yóo di ahoro súnmọ́ tòsí. Nígbà náà kí àwọn tí ó bá wà ní Judia sálọ sórí òkè. Kí àwọn tí ó bá wà ninu ìlú sá kúrò níbẹ̀. Kí àwọn tí ó bá wà ninu abúlé má sá wọ inú ìlú lọ. Nítorí àkókò ẹ̀san ni àkókò náà, nígbà tí ohun gbogbo tí ó wà ní àkọsílẹ̀ yóo ṣẹ. Àwọn obinrin tí ó lóyún ati àwọn tí ó ń tọ́ ọmọ lọ́wọ́ gbé! Nítorí ìdààmú pupọ yóo wà ní ayé, ibinu Ọlọrun yóo wà lórí àwọn eniyan yìí. Idà ni a óo fi pa wọ́n. A óo kó wọn ní ìgbèkùn lọ sí gbogbo orílẹ̀-èdè. Àwọn tí kì í ṣe Juu yóo wó ìlú Jerusalẹmu palẹ̀, títí àkókò tí a fi fún wọn yóo fi pé. “Àmì yóo yọ ní ojú oòrùn ati ní ojú òṣùpá ati lára àwọn ìràwọ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo dààmú nígbà tí wọ́n bá gbọ́ tí òkun ń hó, tí ó ń ru sókè. Àwọn eniyan yóo kú sára nítorí ìbẹ̀rù, nígbà tí wọ́n bá rí ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí ayé. Nítorí gbogbo ẹ̀dá ojú ọ̀run ni a óo mì tìtì. Nígbà náà ni wọn óo rí Ọmọ-Eniyan tí óo máa bọ̀ ninu ìkùukùu pẹlu agbára ati ògo ńlá. Ẹ jẹ́ kí inú yín kí ó dùn, kí ẹ wá máa yan, nígbà tí gbogbo nǹkan wọnyi bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀, nítorí àkókò òmìnira yín ni ó súnmọ́ tòsí.” Ó pa òwe kan fún wọn, ó ní, “Ẹ wo igi ọ̀pọ̀tọ́ ati gbogbo igi yòókù. Nígbà tí ẹ bá rí i, tí wọ́n bá rúwé, ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ pé àkókò ẹ̀ẹ̀rùn dé. Bẹ́ẹ̀ náà ni, nígbà tí ẹ bá rí i, tí gbogbo nǹkan wọnyi ń ṣẹlẹ̀, ẹ mọ̀ pé ìjọba Ọlọrun súnmọ́ tòsí. “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ìran yìí kò ní kọjá lọ kí gbogbo nǹkan wọnyi tó ṣẹ. Ọ̀run ati ayé yóo kọjá lọ, ṣugbọn ọ̀rọ̀ mi kò ní kọjá lọ. “Ẹ ṣọ́ra yín, kí ẹ má jẹ́ kí ayẹyẹ, tabi ìfiṣòfò, tabi ọtí mímu, ati àníyàn ayé gba ọkàn yín, tí ó fi jẹ́ pé lójijì ni ọjọ́ náà yóo dé ba yín bí ìgbà tí tàkúté bá mú ẹran. Nítorí ọjọ́ náà yóo dé bá gbogbo eniyan tí ó wà ní ayé. Ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ máa gbadura nígbà gbogbo pé, kí ẹ lè lágbára láti borí gbogbo àwọn ohun tí ó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀, kí ẹ sì lè dúró níwájú Ọmọ-Eniyan.” Ní ọ̀sán, Jesu a máa kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ ninu Tẹmpili; lálẹ́, á lọ sùn ní orí Òkè Olifi. Gbogbo eniyan a máa tètè jí láti lọ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ninu Tẹmpili. Ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò Àjọ̀dún Àìwúkàrà tí à ń pè ní Àjọ̀dún Ìrékọjá. Àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin ń wá ọ̀nà bí wọn yóo ti ṣe pa Jesu nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan. Satani bá wọ inú Judasi tí à ń pè ní Iskariotu, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila. Ó bá lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn ẹ̀ṣọ́ Tẹmpili láti bá wọn sọ̀rọ̀ bí ọwọ́ wọn yóo ṣe tẹ Jesu. Inú wọn dùn, wọ́n bá ṣe ètò láti fún un ní owó. Ó gbà bẹ́ẹ̀; ó bá bẹ̀rẹ̀ sí wá àkókò tí ó wọ̀ láti fi Jesu lé wọn lọ́wọ́ lọ́nà tí ọ̀pọ̀ eniyan kò fi ní mọ̀. Nígbà tí ó di ọjọ́ Àjọ̀dún Àìwúkàrà, ní ọjọ́ tí wọ́n níláti pa ẹran àsè Ìrékọjá, Jesu rán Peteru ati Johanu, ó ní, “Ẹ lọ ṣe ìtọ́jú ohun tí a óo fi jẹ àsè Ìrékọjá.” Wọ́n bi í pé, “Níbo ni o fẹ́ kí á lọ ṣe ètò sí?” Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Nígbà tí ẹ bá wọ inú ìlú, ọkunrin kan tí ó ru ìkòkò omi yóo pàdé yín. Ẹ tẹ̀lé e, ẹ bá a wọ inú ilé tí ó bá wọ̀. Kí ẹ sọ fún baálé ilé náà pé, ‘Olùkọ́ni sọ pé níbo ni yàrá ibi tí òun óo ti jẹ àsè Ìrékọjá pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn òun wà?’ Yóo fi yàrá ńlá kan hàn yín ní òkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì, tí a ti ṣe lọ́ṣọ̀ọ́. Níbẹ̀ ni kí ẹ ṣe ètò sí.” Ni wọ́n bá lọ, wọ́n rí ohun gbogbo bí Jesu ti sọ fún wọn. Wọ́n sì tọ́jú gbogbo nǹkan fún àsè Ìrékọjá. Nígbà tí ó tó àkókò oúnjẹ, ó jókòó láti jẹun pẹlu àwọn aposteli rẹ̀. Ó sọ fún wọn pé, “Ó ti mú mi lọ́kàn pupọ láti jẹ àsè Ìrékọjá yìí pẹlu yín kí n tó jìyà. Nítorí mo sọ fun yín pé n kò tún ní jẹ ẹ́ mọ́ títí di àkókò tí yóo fi ní ìtumọ̀ tí ó pé ní ìjọba Ọlọrun.” Ó bá mú ife, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó ní, “Ẹ gba èyí, kí ẹ pín in láàrin ara yín. Nítorí mo sọ fun yín pé láti àkókò yìí lọ, n kò tún ní mu ninu èso àjàrà mọ́ títí ìgbà tí ìjọba Ọlọrun yóo fi dé.” Ó bá mú burẹdi, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó bù ú, ó bá fún wọn. Ó ní, “Èyí ni ara mi tí a fun yín. [Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” Bákan náà ni ó gbé ife fún wọn lẹ́yìn oúnjẹ, ó ní, “Ife yìí ni majẹmu titun tí Ọlọrun ba yín dá pẹlu ẹ̀jẹ̀ mi tí a ta sílẹ̀ fun yín.] “Ṣugbọn ṣá o, ẹni tí yóo fi mí fún àwọn ọ̀tá ń bá mi tọwọ́ bọwọ́ níbi oúnjẹ yìí. Ọmọ-Eniyan ń lọ gẹ́gẹ́ bí ó ti yan ìpín tirẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí yóo fi í lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ gbé!” Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí wádìí láàrin ara wọn pé ta ni ìbá jẹ́ ninu wọn tí yóo dán irú rẹ̀ wò. Ìjiyàn kan wà láàrin àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé ta ni ó jẹ́ ẹni pataki jùlọ. Jesu sọ fún wọn pé, “Àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè alaigbagbọ a máa jẹ ọlá lórí wọn. Àwọn aláṣẹ wọn ni wọ́n ń pè ní olóore wọn. Ṣugbọn tiyín kò ní rí bẹ́ẹ̀. Ẹni tí yóo bá jẹ́ ẹni tí ó ṣe pataki jùlọ ninu yín níláti dàbí ọmọ tí ó kéré jùlọ. Ẹni tí yóo jẹ́ aṣaaju níláti máa ṣe bí iranṣẹ. Nítorí ta ni eniyan pataki? Ẹni tí ó jókòó tí ó ń jẹun ni, tabi ẹni tí ó ń ṣe iranṣẹ? Mo ṣebí ẹni tí ó ń jẹun ni. Ṣugbọn èmi wà láàrin yín bí ẹni tí ó ń ṣe iranṣẹ. “Ẹ̀yin ni ẹ dúró tì mí ní gbogbo àkókò ìdánwò mi. Gẹ́gẹ́ bí Baba mi ti fi ìjọba fún mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi náà fi ìjọba fun yín, kí ẹ lè bá mi jẹ, kí ẹ sì bá mi mu ninu ìjọba mi, kí ẹ sì jókòó lórí ìtẹ́ láti máa ṣe ìdájọ́ ẹ̀yà Israẹli mejila. “Simoni! Simoni! Ṣọ́ra o! Satani ti gba àṣẹ láti dán gbogbo yín wò, bí ìgbà tí eniyan bá ń fẹ́ fùlùfúlù kúrò lára ọkà. Ṣugbọn mo ti gbadura fún ọ Simoni, pé kí igbagbọ rẹ kí ó má yẹ̀. Nígbà tí ìwọ bá ronupiwada, mu àwọn arakunrin rẹ lọ́kàn le.” Ṣugbọn Peteru dáhùn pé, “Oluwa, mo ṣetán láti bá ọ wẹ̀wọ̀n, ati láti bá ọ kú.” Ṣugbọn Jesu dáhùn pé, “Peteru mò ń sọ fún ọ pé kí àkùkọ tó kọ lálẹ́ yìí, ẹẹmẹta ni ìwọ óo sọ pé o kò mọ̀ mí rí!” Ó wá sọ fún wọn pé, “Nígbà tí mo ran yín níṣẹ́ tí mo sọ fun yín pé kí ẹ má mú àpò owó ati igbá báárà lọ́wọ́, ati pé kí ẹ má wọ bàtà, kí ni ohun tí ẹ ṣe aláìní?” Wọ́n dáhùn pé, “Kò sí!” Ó wá sọ fún wọn pé, “Ṣugbọn ní àkókò yìí, ẹni tí ó bá ní àpò owó kí ó mú un lọ́wọ́; ẹni tí ó bá ní igbá báárà, kí òun náà gbé e lọ́wọ́. Ẹni tí kò bá ní idà, kí ó ta ẹ̀wù rẹ̀ kí ó fi ra idà kan. Nítorí mo wí fun yín pé ohun gbogbo tí a ti kọ sílẹ̀ nípa mi níláti ṣẹ, pé, ‘A kà á kún àwọn arúfin.’ Ohun tí a sọ nípa mi yóo ṣẹ.” Wọ́n sọ fún un pé, “Oluwa, wò ó! Idà meji nìyí.” Ó sọ fún wọn pé, “Ó tó!” Jesu bá jáde lọ sórí Òkè Olifi, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Nígbà tí ó dé ibẹ̀ ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ máa gbadura kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdánwò.” Ó bá kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó lọ siwaju díẹ̀ sí i. Ó kúnlẹ̀, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí gbadura. Ó ní, “Baba, bí o bá fẹ́, mú kí ife kíkorò yìí fò mí ru. Ṣugbọn ìfẹ́ tèmi kọ́, ìfẹ́ tìrẹ ni kí ó ṣẹ.” [ Angẹli kan yọ sí i láti ọ̀run láti ràn án lọ́wọ́. Pẹlu ọkàn wúwo, ó túbọ̀ gbadura gidigidi. Òógùn ojú rẹ̀ dàbí kí ẹ̀jẹ̀ máa kán bọ́ sílẹ̀.] Ó bá dìde lórí adura, ó lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó rí wọn tí wọn ń sùn nítorí àárẹ̀ ìbànújẹ́. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ̀ ń sùn ni! Ẹ dìde kí ẹ máa gbadura, kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdánwò.” Bí Jesu ti ń sọ̀rọ̀ ni àwọn eniyan bá dé. Judasi, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, ni ó ṣiwaju wọn. Ó bá súnmọ́ Jesu, ó fi ẹnu kò ó ní ẹ̀rẹ̀kẹ́. Jesu sọ fún un pé, “Judasi! O sì fi ẹnu ko Ọmọ-Eniyan ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ láti fi í lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́?” Nígbà tí àwọn tí ó wà pẹlu Jesu rí i, wọ́n ní, “Oluwa, ṣé kí á fa idà yọ?” Ni ọ̀kan ninu wọ́n bá ṣá ẹrú olórí alufaa kan, ó bá gé e ní etí ọ̀tún. Ṣugbọn Jesu sọ pé, “Ẹ fi wọ́n sílẹ̀.” Ó bá fọwọ́ kan etí ẹrú náà, etí náà sì san. Ó wá sọ fún àwọn olórí alufaa, ati àwọn ẹ̀ṣọ́ Tẹmpili ati àwọn àgbà tí wọ́n wá mú un pé, “Ọlọ́ṣà ni ẹ pè mí ni, tí ẹ fi kó idà ati kùmọ̀ wá? Ṣebí ojoojumọ ni mo wà pẹlu yín ninu Tẹmpili. Ẹ kò ṣe fọwọ́ kàn mí? Ṣugbọn àkókò yín ati ti aláṣẹ òkùnkùn nìyí.” Wọ́n bá mú Jesu, wọ́n fà á lọ sí ilé Olórí Alufaa. Ṣugbọn Peteru ń tẹ̀lé wọn lókèèrè. Àwọn kan dá iná sáàrin agbo-ilé, wọ́n jókòó yí i ká, Peteru náà wà láàrin wọn. Ọmọdebinrin kan wá rí i, ó tẹjú mọ́ ọn, ó ní, “Ọkunrin yìí wà pẹlu Jesu.” Ṣugbọn Peteru sẹ́, ó ní, “N kò tilẹ̀ mọ ọkunrin yìí!” Nígbà tí ó ṣe díẹ̀, ẹlòmíràn tún rí i, ó ní, “Ìwọ náà wà láàrin wọn.” Ṣugbọn Peteru ní, “Ọkunrin yìí, n kò sí níbẹ̀!” Nígbà tí ó tó bíi wakati kan, ọkunrin kan tún sọ pẹlu ìdánilójú pé, “Láìsí àní-àní ọkunrin yìí wà pẹlu Jesu, nítorí ará Galili ni.” Ṣugbọn Peteru dáhùn pé, “Ọkunrin yìí, n kò mọ ohun tí ò ń sọ!” Lẹsẹkẹsẹ, ó fẹ́rẹ̀ ma tíì dákẹ́ ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, àkùkọ bá kọ. Oluwa yipada, ó wo Peteru, Peteru wá ranti ọ̀rọ̀ Oluwa nígbà tí ó sọ fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ lálẹ́ yìí, ìwọ yóo sẹ́ mi lẹẹmẹta.” Peteru bá jáde lọ, ó bú sẹ́kún, ó bẹ̀rẹ̀ sí hu gan-an. Àwọn ọkunrin tí wọn ń ṣọ́ Jesu ń fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì ń lù ú. Wọ́n daṣọ bò ó lójú, wọ́n wá ń bi í pé, “Sọ ẹni tí ó lù ọ́?” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń sọ oríṣìíríṣìí ìsọkúsọ sí i. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn àgbààgbà ati àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin péjọ, wọ́n fa Jesu lọ siwaju ìgbìmọ̀ wọn. Wọ́n bi í pé, “Sọ fún wa, ṣé ìwọ ni Mesaya náà?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Bí mo bá sọ fun yín, ẹ kò ní gbàgbọ́. Bí mo bá sì bi yín ní ìbéèrè, ẹ kò ní dáhùn. Láti àkókò yìí, Ọmọ-Eniyan yóo jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọrun Olodumare.” Gbogbo wọn wá bi í pé, “Ṣé ìwọ wá ni Ọmọ Ọlọrun?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹnu ara yín ni ẹ fi sọ pé, èmi ni.” Ni wọ́n bá dáhùn pé, “Ẹlẹ́rìí wo ni a tún ń wá? Nítorí àwa fúnra wa ti gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó fẹnu ara rẹ̀ sọ.” Ni gbogbo àwùjọ bá dìde, wọ́n fa Jesu lọ sọ́dọ̀ Pilatu. Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀sùn kàn án pé, “A rí i pé ńṣe ni ọkunrin yìí ń ba ìlú jẹ́. Ó ní kí àwọn eniyan má san owó-orí. Ó tún pe ara rẹ̀ ní Mesaya, Ọba.” Pilatu bá bi í pé, “Ṣé ìwọ ni ọba àwọn Juu?” Ó dá a lóhùn pé, “O ti fi ẹnu ara rẹ wí i.” Pilatu wá sọ fún àwọn olórí alufaa ati àwọn eniyan pé, “Èmi kò rí àìdára kan tí ọkunrin yìí ṣe.” Ṣugbọn wọ́n túbọ̀ tẹnu mọ́ ẹ̀sùn wọn pé, “Ó ń fi ẹ̀kọ́ rẹ̀ da àwọn eniyan rú; Galili ni ó ti kọ́ bẹ̀rẹ̀, ó ti dé gbogbo Judia níhìn-ín nisinsinyii.” Nígbà tí Pilatu gbọ́ èyí, ó bèèrè bí ará Galili bá ni Jesu. Nígbà tí wọ́n sọ fún un pé lábẹ́ àṣẹ Hẹrọdu ni ó wà, ó rán an sí Hẹrọdu, nítorí pé Hẹrọdu náà kúkú wà ní Jerusalẹmu ní àkókò náà. Nígbà tí Hẹrọdu rí Jesu, inú rẹ̀ dùn pupọ. Nítorí ó ti pẹ́ tí ó ti fẹ́ rí i, nítorí ìró rẹ̀ tí ó ti ń gbọ́. Ó ń retí pé kí Jesu ṣe iṣẹ́ ìyanu lójú òun. Ó bi Jesu ní ọpọlọpọ ìbéèrè ṣugbọn Jesu kò dá a lóhùn rárá. Àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin dúró níbẹ̀, wọ́n ń tẹnu mọ́ ẹ̀sùn tí wọn fi kàn án. Hẹrọdu ati àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ń kẹ́gàn rẹ̀, wọ́n ń fi í ṣe ẹlẹ́yà. Wọ́n gbé ẹ̀wù dáradára kan wọ̀ ọ́; Hẹrọdu bá tún fi ranṣẹ pada sí Pilatu. Ní ọjọ́ náà Hẹrọdu ati Pilatu di ọ̀rẹ́ ara wọn; nítorí tẹ́lẹ̀ rí ọ̀tá ni wọ́n ń bá ara wọn ṣe. Pilatu bá pe àwọn olórí alufaa, ati àwọn ìjòyè, ati àwọn eniyan jọ, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ fa ọkunrin yìí wá sọ́dọ̀ mi bí ẹni tí ó ń ba ìlú jẹ́. Lójú yín ni mo wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀, tí n kò sì rí àìdára kan tí ó ṣe, ninu gbogbo ẹ̀sùn tí ẹ fi kàn án. Hẹrọdu náà kò rí nǹkankan wí sí i, nítorí ńṣe ni ó tún dá a pada sí wa. Ó dájú pé ọkunrin yìí kò ṣe nǹkankan tí ó fi yẹ kí á dá a lẹ́bi ikú. Nítorí náà nígbà tí a bá ti nà án tán, n óo dá a sílẹ̀.” [ Nítorí ó níláti dá ẹlẹ́wọ̀n kan sílẹ̀ fún wọn ní àkókò àjọ̀dún.] Ṣugbọn gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí pariwo pé, “Mú eléyìí lọ! Baraba ni kí o dá sílẹ̀ fún wa.” (Baraba ti dá ìrúkèrúdò sílẹ̀ ninu ìlú nígbà kan, ó sì paniyan, ni wọ́n fi sọ ọ́ sẹ́wọ̀n.) Pilatu tún bá wọn sọ̀rọ̀, ó fẹ́ dá Jesu sílẹ̀. Ṣugbọn wọ́n kígbe pé, “Kàn án mọ́ agbelebu! Kàn án mọ́ agbelebu!” Ó tún bi wọ́n ní ẹẹkẹta pé, “Kí ni nǹkan burúkú tí ó ṣe? Èmi kò rí ìdí kankan tí ó fi jẹ̀bi ikú. Nígbà tí mo bá ti nà án tán n óo dá a sílẹ̀.” Ṣugbọn wọ́n túbọ̀ múra kankan, wọ́n ń kígbe pé kí ó kàn án mọ́ agbelebu. Ohùn wọn bá borí. Pilatu bá gbà láti ṣe bí wọ́n ti fẹ́. Ó dá ẹni tí wọ́n ní àwọn fẹ́ sílẹ̀: ẹni tí wọ́n jù sẹ́wọ̀n nítorí pé ó paniyan. Ó bá fi Jesu lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n fi ṣe ohun tí wọ́n bá fẹ́. Bí wọ́n ti ń fa Jesu lọ, wọ́n bá fi ipá mú ọkunrin kan tí ń jẹ́ Simoni, ará Kirene tí ó ń ti ìgbèríko kan bọ̀. Wọ́n bá gbé agbelebu rù ú, wọ́n ní kí ó máa rù ú tẹ̀lé Jesu lẹ́yìn. Ọ̀pọ̀ eniyan ni ó ń tẹ̀lé Jesu, pẹlu àwọn obinrin tí wọn ń dárò, tí wọn ń sunkún nítorí rẹ̀. Nígbà tí Jesu yipada sí wọn, ó ní, “Ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu, ẹ má sunkún nítorí tèmi mọ́; ẹkún ara yín ati ti àwọn ọmọ yín ni kí ẹ máa sun. Nítorí ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí ẹ óo sọ pé, ‘Àwọn àgàn tí kò bímọ rí, tí wọn kò sì fún ọmọ lọ́mú rí ṣe oríire.’ Nígbà náà ni wọn yóo bẹ̀rẹ̀ sí máa sọ fún àwọn òkè ńlá pé, ‘Ẹ wó lù wá,’ wọ́n óo sì máa sọ fún àwọn òkè kékeré pé, ‘Ẹ bò wá mọ́lẹ̀.’ Nítorí bí ọ̀rọ̀ bá rí báyìí fún igi tútù, báwo ni yóo ti rí fún igi gbígbẹ?” Wọ́n tún ń fa àwọn arúfin meji kan pẹlu rẹ̀, láti lọ pa wọ́n. Nígbà tí wọ́n dé ibi tí wọn ń pè ní, “Ibi Agbárí”, wọ́n kàn án mọ́ agbelebu níbẹ̀ pẹlu àwọn arúfin meji náà, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, ekeji ní ọwọ́ òsì. Jesu ní, “Baba, dáríjì wọ́n, nítorí wọn kò mọ ohun tí wọn ń ṣe.” Wọ́n pín aṣọ rẹ̀ mọ́ ara wọn lọ́wọ́, wọ́n ṣẹ́ gègé láti mọ èyí tí yóo kan ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn. Àwọn eniyan dúró, wọ́n ń wòran. Àwọn ìjòyè ń fi í ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n ń sọ pé, “O gba àwọn ẹlòmíràn là; gba ara rẹ là bí ìwọ bá ni Mesaya, àyànfẹ́ Ọlọrun.” Àwọn ọmọ-ogun náà ń fi ṣe yẹ̀yẹ́. Wọ́n fún un ní ọtí pé kí ó mu ún. Wọ́n ní, “Bí ìwọ bá ni ọba àwọn Juu, gba ara rẹ là.” Wọ́n kọ àkọlé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án sí òkè orí rẹ̀ pé, “Èyí ni ọba àwọn Juu.” Ọ̀kan ninu àwọn arúfin tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu pẹlu rẹ̀ ń sọ ìsọkúsọ pé, “Ṣebí ìwọ ni Mesaya! Gba ara rẹ là kí o sì gba àwa náà là!” Ṣugbọn ekeji bá a wí, ó ní, “Ìwọ yìí, o kò bẹ̀rù Ọlọrun. Ìdájọ́ kan náà ni wọ́n dá fún un bíi tiwa. Ní tiwa, ó tọ́ bẹ́ẹ̀, nítorí èrè iṣẹ́ wa ni à ń jẹ. Ṣugbọn òun ní tirẹ̀ kò ṣẹ̀ rárá.” Ó bá sọ fún Jesu pé, “Ranti mi nígbà tí o bá dé inú ìjọba rẹ.” Jesu bá sọ fún un pé, “Mo wí fún ọ, lónìí yìí ni ìwọ yóo wà pẹlu mi ní ọ̀run rere.” Nígbà tí ó tó bí agogo mejila ọ̀sán, òkùnkùn bo gbogbo ilẹ̀ títí di agogo mẹta ọ̀sán. Oòrùn kò ràn. Aṣọ ìkélé Tẹmpili ya sí meji. *** Jesu kígbe, ó ní, “Baba, ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé.” Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, ó mí kanlẹ̀, ó bá kú. Nígbà tí ọ̀gágun náà rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó yin Ọlọrun lógo, ó ní, “Lóòótọ́, olódodo ni ọkunrin yìí.” Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n péjọ, tí wọn wá wòran, rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ńṣe ni wọ́n pada lọ, tí wọ́n káwọ́ lérí pẹlu ìbànújẹ́. Gbogbo àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀ ati àwọn obinrin tí wọ́n tẹ̀lé e wá láti Galili, gbogbo wọn dúró lókèèrè, wọ́n ń wo gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀. Ọkunrin kan wà ninu àwọn ìgbìmọ̀ tí ó ń jẹ́ Josẹfu. Ó jẹ́ eniyan rere ati olódodo. Òun kò bá wọn lóhùn sí ète tí wọ́n pa, ati ohun tí wọ́n ṣe sí Jesu. Ó jẹ́ ará Arimatia, ìlú kan ní Judia. Ó ń retí ìjọba Ọlọrun. *** Òun ni ó lọ sọ́dọ̀ Pilatu, tí ó bèèrè òkú Jesu. Ó sọ òkú náà kalẹ̀ lórí agbelebu, ó fi aṣọ funfun wé e, ó bá tẹ́ ẹ sinu ibojì tí wọ́n gbẹ́ sinu àpáta, tí wọn kò ì tíì tẹ́ òkú sí rí. Ọjọ́ náà jẹ̀ Ọjọ́ Ìpalẹ̀mọ́, Ọjọ́ Ìsinmi fẹ́rẹ̀ bẹ̀rẹ̀. Àwọn obinrin tí wọn bá Jesu wá láti Galili tẹ̀lé Josẹfu yìí, wọ́n ṣe akiyesi ibojì náà, ati bí a ti ṣe tẹ́ òkú Jesu sinu rẹ̀. Wọ́n bá pada lọ láti lọ tọ́jú turari olóòórùn dídùn ati ìpara tí wọn fi ń tọ́jú òkú. Ní Ọjọ́ Ìsinmi, wọ́n sinmi gẹ́gẹ́ bí òfin ti wí. Ní kutukutu òwúrọ̀ ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, wọ́n wá sí ibojì, wọ́n mú òróró olóòórùn dídùn tí wọ́n ti tọ́jú lọ́wọ́. Wọ́n rí i pé wọ́n ti yí òkúta kúrò ní ẹnu ibojì. Nígbà tí wọ́n wọ inú ibojì, wọ́n kò rí òkú Jesu Oluwa. Bí wọ́n ti dúró tí wọn kò mọ ohun tí wọn yóo ṣe, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkunrin meji kan bá yọ sí wọn, wọ́n wọ aṣọ dídán. Ẹ̀rù ba àwọn obinrin náà, wọ́n bá dojúbolẹ̀. Àwọn ọkunrin náà wá bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń wá alààyè láàrin àwọn òkú? Kò sí níhìn-ín; ó ti jí dìde. Ẹ ranti bí ó tí sọ fun yín nígbà tí ó wà ní Galili pé, ‘Dandan ni kí á fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn eniyan burúkú lọ́wọ́, kí wọ́n kàn án mọ́ agbelebu, ati pé kí ó jí dìde ní ọjọ́ kẹta.’ ” Wọ́n wá ranti ọ̀rọ̀ rẹ̀. Wọ́n bá kúrò ní ibojì náà, wọ́n pada lọ sọ gbogbo nǹkan tí wọ́n rí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọkanla ati gbogbo àwọn yòókù. Maria Magidaleni, ati Joana, ati Maria ìyá Jakọbu ati gbogbo àwọn yòókù tí ó bá wọn lọ, ni wọ́n sọ nǹkan wọnyi fún àwọn aposteli. Ṣugbọn bíi ìsọkúsọ ni gbogbo ọ̀rọ̀ yìí rí létí wọn. Wọn kò gba ohun tí àwọn obinrin náà sọ gbọ́. [ Ṣugbọn Peteru dìde, ó sáré lọ sí ibojì náà. Nígbà tí ó yọjú wo inú rẹ̀, aṣọ funfun tí wọ́n fi wé òkú nìkan ni ó rí. Ó bá pada sí ilé, ẹnu yà á sí ohun tí ó ṣẹlẹ̀.] Ní ọjọ́ kan náà, àwọn meji ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ń lọ sí abúlé kan tí ó ń jẹ́ Imausi. Ó tó bí ibùsọ̀ meje sí Jerusalẹmu. Wọ́n ń bá ara wọn jíròrò lórí gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Bí wọ́n ti ń bá ara wọn jíròrò, tí wọn ń bá ara wọn jiyàn, Jesu alára bá súnmọ́ wọn, ó ń bá wọn rìn lọ. Ṣugbọn ó dàbí ẹni pé a dì wọ́n lójú, wọn kò mọ̀ pé òun ni. Ó bá bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ̀ ń bá ara yín sọ bí ẹ ti ń rìn bọ̀? Kí ló dé tí ojú yín fi rẹ̀wẹ̀sì bẹ́ẹ̀?” Ọ̀kan ninu wọn tí ń jẹ́ Kilopasi dá a lóhùn pé, “Ṣé àlejò ni ọ́ ní Jerusalẹmu ni, tí o kò fi mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ ní ààrin bí ọjọ́ mélòó kan yìí?” Jesu bá bi í pé, “Bíi kí ni?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Jesu ará Nasarẹti ni. Wolii ni, iṣẹ́ rẹ̀ ati ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì fi agbára hàn níwájú Ọlọrun ati gbogbo eniyan. Ṣugbọn àwọn olórí alufaa ati àwọn ìjòyè wa fà á fún ìdájọ́ ikú, wọ́n bá kàn án mọ́ agbelebu. Òun ní àwa ti ń retí pé yóo fún Israẹli ní òmìnira. Ati pé ju gbogbo rẹ̀ lọ, ọjọ́ kẹta nìyí tí gbogbo rẹ̀ ti ṣẹlẹ̀. Ṣugbọn àwọn obinrin kan láàrin wa sọ ohun tí ó yà wá lẹ́nu. Wọ́n jí lọ sí ibojì, wọn kò rí òkú rẹ̀. Wọ́n wá ń sọ pé àwọn rí àwọn angẹli tí wọ́n sọ pé ó ti wà láàyè. Ni àwọn kan ninu wa bá lọ sí ibojì. Wọ́n bá gbogbo nǹkan bí àwọn obinrin ti wí, ṣugbọn wọn kò rí òun alára.” Ni Jesu bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin aláìmòye wọnyi! Ẹ lọ́ra pupọ láti gba ọ̀rọ̀ tí àwọn wolii ti sọ! Dandan ni pé kí Mesaya jìyà, kí ó tó bọ́ sinu ògo rẹ̀.” Jesu wá bẹ̀rẹ̀ sí túmọ̀ gbogbo àkọsílẹ̀ nípa ara rẹ̀ fún wọn. Ó bẹ̀rẹ̀ pẹlu ìwé Mose, títí dé gbogbo ìwé àwọn wolii. Nígbà tí wọ́n súnmọ́ abúlé tí wọn ń lọ, Jesu ṣe bí ẹni pé ó fẹ́ máa bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ. Ṣugbọn wọ́n bẹ̀ ẹ́ pupọ pé, “Dúró lọ́dọ̀ wa, ọjọ́ ti lọ, ilẹ̀ ti ṣú.” Ni ó bá bá wọn wọlé, ó dúró lọ́dọ̀ wọn. Nígbà tí ó ń bá wọn jẹun, ó mú burẹdi, ó súre sí i, ó bù ú, ó bá fi fún wọn. Ojú wọn bá là; wọ́n wá mọ̀ pé Jesu ni. Ó bá rá mọ́ wọn lójú. Wọ́n wá ń bá ara wọn sọ pé, “Ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú wa lọ́kàn bí ó ti ń bá wa sọ̀rọ̀ lọ́nà, ati bí ó ti ń túmọ̀ Ìwé Mímọ́ fún wa!” Wọ́n bá dìde lẹsẹkẹsẹ, wọ́n pada lọ sí Jerusalẹmu. Wọ́n bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọkanla ati àwọn tí ó wà pẹlu wọn níbi tí wọ́n péjọ sí, àwọn ni wọ́n wá sọ fún wọn pé, “Oluwa ti jí dìde nítòótọ́, ó ti fara han Simoni.” Ni àwọn náà wá ròyìn ìrírí wọn ní ojú ọ̀nà ati bí wọ́n ti ṣe mọ̀ ọ́n nígbà tí ó bu burẹdi. Bí wọ́n ti ń sọ àwọn nǹkan wọnyi lọ́wọ́, Jesu alára bá dúró láàrin wọn. Ó ní, “Alaafia fun yín.” Wọ́n ta gìrì, ẹ̀rù bà wọ́n; wọ́n ṣebí iwin ni. Ṣugbọn ó ní, “Kí ni ń bà yín lẹ́rù. Kí ni ó ń mú iyè meji wá sí ọkàn yín? Ẹ wo ọwọ́ mi ati ẹsẹ̀ mi, kí ẹ rí i pé èmi gan-an ni. Ẹ fọwọ́ kàn mí kí ẹ rí i, nítorí iwin kò ní ẹran-ara ati egungun bí ẹ ti rí i pé mo ní.” Nígbà tí ó wí báyìí tán, ó fi ọwọ́ rẹ̀ ati ẹsẹ̀ rẹ̀ hàn wọn. Nígbà tí wọn kò gbàgbọ́ sibẹ nítorí pé ó yà wọ́n lẹ́nu ati pé wọn kò rí bí ó ti ṣe lè rí bẹ́ẹ̀, ó bi wọ́n pé, “Ṣé ẹ ní nǹkan jíjẹ níhìn-ín?” Wọ́n bá bù ninu ẹja díndín fún un. Ó bá gbà á, ó jẹ ẹ́ lójú wọn. Ó bá sọ fún wọn pé, “Ọ̀rọ̀ tí mo sọ fun yín nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ yín nìyí, pé dandan ni kí ohun gbogbo tí a sọ nípa mi kí ó ṣẹ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ wọ́n sílẹ̀ ninu ìwé Òfin Mose ati ninu ìwé àwọn wolii ati ninu ìwé Orin Dafidi.” Ó bá là wọ́n lọ́yẹ kí Ìwé Mímọ́ lè yé wọn. Ó wá tún sọ fún wọn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní àkọsílẹ̀ pé Mesaya gbọdọ̀ jìyà, kí ó sì jí dìde kúrò ninu òkú ní ọjọ́ kẹta. Ati pé ní orúkọ rẹ̀, kí á máa waasu ìrònúpìwàdà ati ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ láti Jerusalẹmu. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí nǹkan wọnyi. N óo rán ẹ̀bùn tí Baba mi ṣe ìlérí sí orí yín. Ṣugbọn ẹ dúró ninu ìlú yìí títí agbára láti òkè wá yóo fi sọ̀kalẹ̀ sórí yín.” Jesu bá kó wọn jáde lọ sí Bẹtani. Ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó súre fún wọn. Bí ó ti ń súre fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni ó ń gòkè lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn, ni a bá fi gbé e lọ sí ọ̀run. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn júbà rẹ̀, wọ́n bá fi ọpọlọpọ ayọ̀ pada lọ sí Jerusalẹmu. Inú Tẹmpili ni wọ́n ń wà nígbà gbogbo, tí wọ́n ń fi ìyìn fún Ọlọrun. Ní ìbẹ̀rẹ̀, kí á tó dá ayé, ni Ọ̀rọ̀ ti wà, Ọ̀rọ̀ wà pẹlu Ọlọrun, Ọlọrun sì ni Ọ̀rọ̀ náà. Òun ni ó wà pẹlu Ọlọrun ní ìbẹ̀rẹ̀, kí á tó dá ayé. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a ti dá ohun gbogbo, ninu gbogbo ohun tí a dá, kò sí ohun kan tí a dá lẹ́yìn rẹ̀. Òun ni orísun ìyè, ìyè náà ni ìmọ́lẹ̀ aráyé. Ìmọ́lẹ̀ náà ń tàn ninu òkùnkùn, òkùnkùn kò sì lè borí rẹ̀. Ọkunrin kan wà tí a rán wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Johanu. Òun ni ó wá gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí, kí ó lè jẹ́rìí sí ìmọ́lẹ̀ náà, kí gbogbo eniyan lè torí ẹ̀rí rẹ̀ gbàgbọ́. Kì í ṣe òun ni ìmọ́lẹ̀ náà, ṣugbọn ó wá láti jẹ́rìí ìmọ́lẹ̀ náà. Èyí ni ìmọ́lẹ̀ tòótọ́ tí ó wá sinu ayé, tí ó ń tàn sí gbogbo aráyé. Ọ̀rọ̀ ti wà ninu ayé. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá ayé, sibẹ ayé kò mọ̀ ọ́n. Ó wá sí ìlú ara rẹ̀, ṣugbọn àwọn ará ilé rẹ̀ kò gbà á. Ṣugbọn iye àwọn tí ó gbà á, ni ó fi àṣẹ fún láti di ọmọ Ọlọrun, àní àwọn tí ó gba orúkọ rẹ̀ gbọ́. A kò bí wọn bí eniyan ṣe ń bímọ nípa ìfẹ́ ara tabi ìfẹ́ eniyan, ṣugbọn nípa ìfẹ́ Ọlọrun ni a bí wọn. Ọ̀rọ̀ náà wá di eniyan, ó ń gbé ààrin wa, a rí ògo rẹ̀, ògo bíi ti Ọmọ bíbí kan ṣoṣo tí ó ti ọ̀dọ̀ Baba wá, tí ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ ati òtítọ́. Johanu jẹ́rìí nípa rẹ̀, ó ń ké rara pé, “Ẹni tí mo sọ nípa rẹ̀ nìyí pé, ‘Ẹnìkan ń bọ̀ lẹ́yìn mi tí ó jù mí lọ, nítorí ó ti wà ṣiwaju mi.’ ” Nítorí láti inú ẹ̀kún ibukun rẹ̀ ni gbogbo wa ti rí oore-ọ̀fẹ́ gbà kún oore-ọ̀fẹ́. Nípasẹ̀ Mose ni a ti fún wa ní Òfin, ṣugbọn nípasẹ Jesu Kristi ni oore-ọ̀fẹ́ ati òtítọ́ ti wá. Kò sí ẹni tí ó rí Ọlọrun rí nígbà kan. Ẹnìkan ṣoṣo tí ó jẹ́ ọmọ bíbí Ọlọrun, kòríkòsùn Baba, ni ó fi ẹni tí Baba jẹ́ hàn. Èyí ni ẹ̀rí tí Johanu jẹ́ nígbà tí àwọn Juu ranṣẹ sí i láti Jerusalẹmu. Wọ́n rán àwọn alufaa ati àwọn kan ninu ẹ̀yà Lefi kí wọ́n lọ bi í pé “Ta ni ọ́?” Ó sọ òtítọ́, kò parọ́, ó ní, “Èmi kì í ṣe Mesaya náà.” Wọ́n wá bi í pé, “Ta wá ni ọ́? Ṣé Elija ni ọ́ ni?” Ó ní, “Èmi kì í ṣe Elija.” Wọ́n tún bi í pé, “Ìwọ ni wolii tí à ń retí bí?” Ó ní, “Èmi kọ́.” Wọ́n bá tún bèèrè pé, “Ó dára, ta ni ọ́? Ó yẹ kí á lè rí èsì mú pada fún àwọn tí wọ́n rán wa wá. Kí ni o sọ nípa ara rẹ?” Ó bá dáhùn gẹ́gẹ́ bí wolii Aisaya ti sọ pé: “Èmi ni ‘ohùn ẹni tí ń kígbe ninu aṣálẹ̀ pé: Ẹ ṣe ọ̀nà tí ó tọ́ fún Oluwa.’ ” Àwọn Farisi ni ó rán àwọn eniyan sí i. Wọ́n wá bi í pé, “Kí ló dé tí o fi ń ṣe ìrìbọmi nígbà tí kì í ṣe ìwọ ni Mesaya tabi Elija tabi wolii tí à ń retí?” Johanu dá wọn lóhùn pé, “Omi ni èmi fi ń ṣe ìwẹ̀mọ́, ẹnìkan wà láàrin yín tí ẹ kò mọ̀, ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi, ṣugbọn n kò tó tú okùn bàtà rẹ̀.” Ní Bẹtani tí ó wà ní apá ìlà oòrùn odò Jọdani ni nǹkan wọnyi ti ṣẹlẹ̀, níbi tí Johanu ti ń ṣe ìrìbọmi. Ní ọjọ́ keji, Johanu rí Jesu tí ó ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “Wo ọ̀dọ́ aguntan Ọlọrun, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ aráyé lọ. Òun ni mo sọ nípa rẹ̀ pé, ‘Ẹnìkan ń bọ̀ lẹ́yìn mi, ẹni tí ó jù mí lọ, nítorí ó ti wà kí á tó bí mi.’ Èmi alára kò mọ̀ ọ́n, ṣugbọn kí á lè fi í han Israẹli ni mo ṣe wá, tí mò ń fi omi ṣe ìwẹ̀mọ́.” Johanu tún jẹ́rìí pé, “Mo ti rí Ẹ̀mí tí ó sọ̀kalẹ̀ bí àdàbà láti ọ̀run tí ó bà lé e, tí ó sì ń bá a gbé. Èmi alára kò mọ̀ ọ́n, ṣugbọn ẹni tí ó rán mi láti máa ṣe ìrìbọmi ti sọ fún mi pé, ẹni tí mo bá rí tí Ẹ̀mí bá sọ̀kalẹ̀ lé lórí, tí ó bá ń bá a gbé, òun ni ẹni tí ó ń fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe ìwẹ̀mọ́. Mo ti rí i, mo wá ń jẹ́rìí pé òun ni Ọmọ Ọlọrun.” Ní ọjọ́ keji, bí Johanu ati àwọn meji ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti tún dúró, ó tẹjú mọ́ Jesu bí ó ti ń kọjá lọ, ó ní, “Wo ọ̀dọ́ aguntan Ọlọrun.” Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn meji náà gbọ́, wọ́n tẹ̀lé Jesu. Nígbà tí Jesu yipada, tí ó rí wọn tí wọn ń tẹ̀lé òun, ó bi wọn pé, “Kí ni ẹ̀ ń wá?” Wọ́n ní, “Rabi, níbo ni ò ń gbé?” (Ìtumọ̀ “Rabi” ni “Olùkọ́ni.”) Ó ní, “Ẹ ká lọ, ẹ óo sì rí i.” Wọ́n bá bá a lọ, wọ́n rí ibi tí ó ń gbé. Wọ́n dúró lọ́dọ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ náà, nítorí ó ti tó bí nǹkan agogo mẹrin ìrọ̀lẹ́. Ọ̀kan ninu àwọn meji tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Johanu, tí ó tẹ̀lé Jesu ni Anderu arakunrin Simoni Peteru. Lẹsẹkẹsẹ, Anderu rí Simoni arakunrin rẹ̀, ó sọ fún un pé, “Àwa ti rí Mesaya!” (Ìtumọ̀ “Mesaya” ni “Kristi.”) Ó bá mú un lọ sọ́dọ̀ Jesu. Jesu tẹjú mọ́ ọn, ó ní, “Ìwọ ni Simoni ọmọ Johanu; Kefa ni a óo máa pè ọ́.” (Ìtumọ̀ “Kefa” ni “àpáta”, “Peteru” ni ní èdè Giriki.) Ní ọjọ́ keji, bí Jesu ti fẹ́ máa lọ sí ilẹ̀ Galili, ó rí Filipi. Ó sọ fún un pé, “Máa tẹ̀lé mi.” Ará Bẹtisaida, ìlú Anderu ati ti Peteru, ni Filipi. Filipi wá rí Nataniẹli, ó wí fún un pé, “Àwa ti rí ẹni tí Mose kọ nípa rẹ̀ ninu Ìwé Òfin, tí àwọn wolii tún kọ nípa rẹ̀, Jesu ọmọ Josẹfu ará Nasarẹti.” Nataniẹli bi í pé, “Ṣé nǹkan rere kan lè ti Nasarẹti wá?” Filipi dá a lóhùn pé, “Wá wò ó.” Jesu rí Nataniẹli bí ó ti ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sọ nípa rẹ̀ pé, “Wo ọmọlúwàbí, ọmọ Israẹli tí kò ní ẹ̀tàn ninu.” Nataniẹli bi í pé, “Níbo ni o ti mọ̀ mí?” Jesu dá a lóhùn pé, “Kí Filipi tó pè ọ́, nígbà tí o wà ní abẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́, mo ti rí ọ.” Nataniẹli wí fún un pé, “Olùkọ́ni, ìwọ ni ọmọ Ọlọrun, ìwọ ni ọba Israẹli.” Jesu wí fún un pé, “Nítorí mo wí fún ọ pé mo rí ọ ní abẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ ni o ṣe gbàgbọ́? Ìwọ yóo rí ohun tí ó jù yìí lọ.” Ó tún wí fún un pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ẹ óo rí ọ̀run tí yóo pínyà, ẹ óo wá rí àwọn angẹli Ọlọrun tí wọn óo máa gòkè, tí wọn óo tún máa sọ̀kalẹ̀ sórí Ọmọ-Eniyan.” Ní ọjọ́ kẹta, wọ́n ń ṣe igbeyawo kan ní Kana, ìlú kan ní Galili. Ìyá Jesu wà níbẹ̀. Wọ́n pe Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ibi igbeyawo náà. Nígbà tí ọtí tán, ìyá Jesu sọ fún un pé, “Wọn kò ní ọtí mọ́!” Jesu wí fún un pé, “Kí ni tèmi ati tìrẹ ti jẹ́, obinrin yìí? Àkókò mi kò ì tíì tó.” Ìyá rẹ̀ sọ fún àwọn iranṣẹ pé, “Ẹ ṣe ohunkohun tí ó bá wí fun yín.” Ìkòkò òkúta mẹfa kan wà níbẹ̀, tí wọ́n ti tọ́jú fún omi ìwẹ-ọwọ́-wẹ-ẹsẹ̀ àwọn Juu, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gbà tó bíi garawa omi marun-un tabi mẹfa. Jesu wí fún àwọn iranṣẹ pé, “Ẹ pọn omi kún inú àwọn ìkòkò wọnyi.” Wọ́n bá pọnmi kún wọn. Ó bá tún wí fún wọn pé, “Ẹ bù ninu rẹ̀ lọ fún alága àsè.” Wọ́n bá bù ú lọ. Nígbà tí alága àsè tọ́ omi tí ó di ọtí wò, láì mọ ibi tí ó ti wá, (bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn iranṣẹ tí ó bu omi náà mọ̀), alága àsè pe ọkọ iyawo. Ó ní, “Ọtí tí ó bá dùn ni gbogbo eniyan kọ́ ń gbé kalẹ̀. Nígbà tí àwọn eniyan bá ti mu ọtí yó tán, wọn á wá gbé ọtí èyí tí kò dára tóbẹ́ẹ̀ wá. Ṣugbọn ìwọ fi àtàtà ọtí yìí pamọ́ di àkókò yìí!” Èyí ni ìbẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jesu ṣe ní Kana ti Galili. Èyí gbé ògo rẹ̀ yọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbà á gbọ́. Lẹ́yìn èyí, ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kapanaumu, òun, ìyá rẹ̀, àwọn arakunrin rẹ̀, ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Wọ́n gbé ibẹ̀ fún ọjọ́ bíi mélòó kan. Nígbà tí ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá àwọn Juu, Jesu gòkè lọ sí Jerusalẹmu. Ó rí àwọn tí ń ta mààlúù, aguntan, ati ẹyẹlé ninu àgbàlá Tẹmpili, ati àwọn tí ń ṣe pàṣípààrọ̀ owó. Jesu bá fi okùn kan ṣe ẹgba, ó bẹ̀rẹ̀ sí lé gbogbo wọn jáde kúrò ninu àgbàlá Ilé Ìrúbọ. Ó lé àwọn tí ń ta aguntan ati mààlúù jáde. Ó da gbogbo owó àwọn onípàṣípààrọ̀ nù, ó sì ti tabili wọn ṣubú. Ó sọ fún àwọn tí ń ta ẹyẹlé pé, “Ẹ gbé gbogbo nǹkan wọnyi kúrò níhìn-ín, ẹ má ṣe sọ ilé Baba mi di ilé ìtajà!” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ranti àkọsílẹ̀ kan tí ó kà báyìí, “Ìtara ilé rẹ ti jẹ mí lógún patapata.” Àwọn Juu wá bi í pé, “Àmì wo ni ìwọ óo fihàn wá gẹ́gẹ́ bíi ìdí tí o fi ń ṣe nǹkan wọnyi?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Bí ẹ bá wó Tẹmpili yìí, èmi yóo tún un kọ́ ní ọjọ́ mẹta.” Àwọn Juu wí fún un pé, “Aadọta ọdún ó dín mẹrin ni ó gbà wá láti kọ́ Tẹmpili yìí, ìwọ yóo wá kọ́ ọ ní ọjọ́ mẹta?” Ṣugbọn ara rẹ̀ ni ó ń sọ̀rọ̀ bá, tí ó pè ní Tẹmpili. Nítorí náà, nígbà tí a ti jí i dìde kúrò ninu òkú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ranti pé ó ti sọ èyí fún wọn, wọ́n wá gba Ìwé Mímọ́ gbọ́ ati ọ̀rọ̀ tí Jesu ti sọ. Nígbà tí Jesu wà ní agbègbè Jerusalẹmu ní àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá, ọpọlọpọ eniyan gba orúkọ rẹ̀ gbọ́ nígbà tí wọ́n ṣe akiyesi àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ń ṣe. Ṣugbọn Jesu fúnrarẹ̀ kò gbára lé wọn, nítorí ó mọ gbogbo eniyan. Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ di ìgbà tí ẹnikẹ́ni bá sọ fún un nípa ọmọ aráyé nítorí ó mọ ohun tí ó wà ninu wọn. Ọkunrin kan wà ninu àwọn Farisi tí ń jẹ́ Nikodemu. Ó jẹ́ ọ̀kan ninu ìgbìmọ̀ àwọn Juu. Ọkunrin yìí fi òru bojú lọ sọ́dọ̀ Jesu. Ó wí fún un pé, “Rabi, a mọ̀ pé olùkọ́ni láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá ni ọ́, nítorí kò sí ẹni tí ó lè ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ò ń ṣe wọnyi àfi ẹni tí Ọlọrun bá wà pẹlu rẹ̀.” Jesu bá gba ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu, ó ní, “Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, ẹnikẹ́ni tí a kò bá tún bí láti ọ̀run kò lè rí ìjọba Ọlọrun.” Nikodemu bi í pé, “Báwo ni a ti ṣe lè tún ẹni tí ó ti di àgbàlagbà bí? Kò sá tún lè pada wọ inú ìyá rẹ̀ lẹẹkeji kí á wá tún un bí!” Jesu dáhùn pé, “Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, ẹnikẹ́ni tí a kò bá fi omi ati Ẹ̀mí bí, kò lè wọ ìjọba Ọlọrun. Ẹni tí a bá bí ní bíbí ti ẹran-ara, ẹran-ara ni. Ẹni tí a bá bí ní bíbí ti Ẹ̀mí, ẹ̀mí ni. Má ṣe jẹ́ kí ẹnu yà ọ́ nítorí mo wí fún ọ pé: dandan ni kí á tún yín bí. Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ sí ibikíbi tí ó bá wù ú; ò ń gbọ́ ìró rẹ̀, ṣugbọn o kò mọ ibi tí ó ti ń bọ̀, tabi ibi tí ó ń lọ. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí pẹlu gbogbo ẹni tí a bí ní bíbí ti Ẹ̀mí.” Nikodemu wá bi í pé, “Báwo ni nǹkan wọnyi ti ṣe lè rí bẹ́ẹ̀?” Jesu ní, “Mo ṣebí olùkọ́ni olókìkí ní Israẹli ni ọ́, sibẹ o kò mọ nǹkan wọnyi? Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, à ń sọ ohun tí a mọ̀, a sì ń jẹ́rìí ohun tí a rí, ṣugbọn ẹ̀yin kò gba ẹ̀rí wa. Bí mo bá sọ nǹkan ti ayé fun yín tí ẹ kò gbàgbọ́, ẹ óo ti ṣe gbàgbọ́ bí mo bá sọ nǹkan ti ọ̀run fun yín? Kò sí ẹni tí ó tíì gòkè lọ sí ọ̀run rí àfi ẹni tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, èyí ni Ọmọ-Eniyan.” Bí Mose ti gbé ejò sókè ní aṣálẹ̀, bẹ́ẹ̀ gan-an ni a óo gbé Ọmọ-Eniyan sókè, kí gbogbo ẹni tí ó bá gbà á gbọ́ lè ní ìyè ainipẹkun. Nítorí Ọlọrun fẹ́ aráyé tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kanṣoṣo fúnni, pé kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́ má baà ṣègbé, ṣugbọn kí ó lè ní ìyè ainipẹkun. Nítorí Ọlọrun kò rán Ọmọ rẹ̀ wá sí ayé láti dá aráyé lẹ́bi bíkòṣe pé kí aráyé lè ti ipasẹ̀ rẹ̀ ní ìgbàlà. A kò ní dá ẹni tí ó bá gbà á gbọ́ lẹ́bi. Ṣugbọn a ti dá ẹni tí kò bá gbà á gbọ́ lẹ́bi ná, nítorí kò gba orúkọ Ọmọ bíbí Ọlọrun kanṣoṣo gbọ́. Ìdálẹ́bi náà ni pé ìmọ́lẹ̀ ti dé sinu ayé, ṣugbọn aráyé fẹ́ràn òkùnkùn ju ìmọ́lẹ̀ lọ, nítorí iṣẹ́ wọn burú. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe burúkú a máa kórìíra ìmọ́lẹ̀; kò jẹ́ wá sí ibi tí ìmọ́lẹ̀ bá wà, kí eniyan má baà bá a wí nítorí iṣẹ́ rẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí ó bá ń hùwà òtítọ́ á máa wá sí ibi ìmọ́lẹ̀, kí iṣẹ́ rẹ̀ lè hàn pé agbára Ọlọrun ni ó fi ń ṣe wọ́n. Lẹ́yìn èyí, Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Judia, wọ́n ń gbé ibẹ̀, ó bá ń ṣe ìrìbọmi fún àwọn eniyan. Johanu náà ń ṣe ìrìbọmi fún àwọn eniyan ní Anoni lẹ́bàá Salẹmu, nítorí omi pọ̀ níbẹ̀. Àwọn eniyan ń wọ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì ń ṣe ìrìbọmi fún wọn. (Wọn kò ì tíì ju Johanu sẹ́wọ̀n ní àkókò yìí.) Ọ̀rọ̀ nípa ìwẹ̀mọ́ di àríyànjiyàn láàrin àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ati ọkunrin Juu kan. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà bá lọ sọ́dọ̀ Johanu, wọ́n wí fún un pé, “Olùkọ́ni, ọkunrin tí ó wà pẹlu rẹ ní òdìkejì odò Jọdani, tí o jẹ́rìí nípa rẹ̀, ń ṣe ìrìbọmi, gbogbo eniyan sì ń tọ̀ ọ́ lọ.” Johanu fèsì pé, “Kò sí ẹni tí ó lè rí ohunkohun gbà àfi ohun tí Ọlọrun bá fún un. Ẹ̀yin fúnra yín jẹ́rìí mi pé mo sọ pé, ‘Èmi kì í ṣe Kristi náà, ṣugbọn èmi ni a rán ṣiwaju rẹ̀.’ Ọkọ iyawo ni ó ni iyawo, ṣugbọn ẹni tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ ọkọ iyawo, tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀, tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, á máa láyọ̀ láti gbọ́ ohùn ọkọ iyawo. Nítorí náà ayọ̀ mi yìí di ayọ̀ kíkún. Dandan ni pé kí òun túbọ̀ jẹ́ pataki sí i, ṣugbọn kí jíjẹ́ pataki tèmi máa dínkù.” Ẹni tí ó wá láti òkè ju gbogbo eniyan lọ. Ẹni tí ó jẹ́ ti ayé, ti ayé ni, ọ̀rọ̀ ti ayé ni ó sì ń sọ. Ẹni tí ó wá láti ọ̀run ju gbogbo eniyan lọ. Ohun tí ó rí, tí ó sì gbọ́ ni ó ń jẹ́rìí sí, ṣugbọn ẹ̀yin kò gba ẹ̀rí rẹ̀. Ẹni tí ó bá gba ẹ̀rí rẹ̀ gbà dájúdájú pé olóòótọ́ ni Ọlọrun. Nítorí pé ẹni tí Ọlọrun rán wá ń sọ ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Nítorí pé Ọlọrun fún un ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ẹ̀mí rẹ̀. Baba fẹ́ràn Ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo sí ìkáwọ́ rẹ̀. Ẹni tí ó bá gba Ọmọ gbọ́ ní ìyè ainipẹkun. Ṣugbọn ẹni tí ó bá ṣàìgbọràn sí Ọmọ kò ní rí ìyè, ṣugbọn ibinu Ọlọrun wà lórí rẹ̀. Àwọn Farisi gbọ́ pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ń pọ̀ ju àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu lọ; ati pé Jesu ń ṣe ìrìbọmi fún ọpọlọpọ eniyan ju Johanu lọ. Ṣugbọn ṣá, kì í ṣe Jesu fúnrarẹ̀ ni ó ń ṣe ìrìbọmi fún àwọn eniyan, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ni. Nígbà tí Jesu mọ̀ pé àwọn Farisi ti gbọ́ ìròyìn yìí, ó kúrò ní Judia, ó tún pada lọ sí Galili. Ó níláti gba ààrin ilẹ̀ Samaria kọjá. Ó dé ìlú Samaria kan tí ń jẹ́ Sikari, lẹ́bàá ilẹ̀ tí Jakọbu fún Josẹfu, ọmọ rẹ̀. Kànga kan tí ó ní omi wà níbẹ̀, tí Jakọbu gbẹ́ nígbà ayé rẹ. Jesu jókòó létí kànga náà ní nǹkan bí agogo mejila ọ̀sán, àárẹ̀ ti mú un nítorí ìrìn àjò tí ó rìn. Obinrin kan ará Samaria wá pọn omi. Jesu wí fún un pé, “Fún mi ní omi mu.” (Ní àkókò yìí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti lọ ra oúnjẹ ninu ìlú.) Obinrin ará Samaria náà dá Jesu lóhùn pé, “Kí ló dé tí ìwọ tí ó jẹ́ Juu fi ń bèèrè omi lọ́wọ́ èmi tí mo jẹ́ obinrin ará Samaria?” (Gbolohun yìí jáde nítorí àwọn Juu kì í ní ohunkohun ṣe pẹlu àwọn ará Samaria.) Jesu dá a lóhùn pé, “Bí ó bá jẹ́ pé o mọ ẹ̀bùn Ọlọrun ati ẹni tí ó wí fún ọ pé, ‘Fún mi ní omi mu,’ Ìwọ ìbá bèèrè omi ìyè lọ́wọ́ rẹ̀, òun ìbá sì fún ọ.” Obinrin náà sọ fún un pé, “Alàgbà, o kò ní ohun tí o lè fi fa omi, kànga yìí sì jìn, níbo ni ìwọ óo ti mú omi ìyè wá? Ìwọ kò ṣá ju Jakọbu baba-ńlá wa, tí ó gbẹ́ kànga yìí fún wa lọ, tí òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ati ẹran-ọ̀sìn rẹ̀ sì ń mu níbẹ̀?” Jesu dá a lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá mu ninu omi yìí òùngbẹ yóo tún gbẹ ẹ́. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá mu ninu omi tí èmi yóo fi fún un, òùngbẹ kò ní gbẹ ẹ́ mọ́ lae, ṣugbọn omi tí n óo fún un yóo di orísun omi ninu rẹ̀ tí yóo máa sun títí dé ìyè ainipẹkun.” Obinrin náà sọ fún un pé, “Alàgbà, fún mi ní omi yìí kí òùngbẹ má baà gbẹ mí mọ́, kí n má baà tún wá pọn omi níhìn-ín mọ́.” Jesu wí fún un pé, “Lọ pe ọkọ rẹ wá ná.” Obinrin náà dáhùn pé, “Èmi kò ní ọkọ.” Jesu wí fún un pé, “O wí ire pé o kò ní ọkọ, nítorí o ti ní ọkọ marun-un rí, ẹni tí o wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nisinsinyii kì í sì í ṣe ọkọ rẹ. Òtítọ́ ni o sọ.” Obinrin náà sọ fún un pé, “Alàgbà, mo wòye pé wolii ni ọ́. Ní orí òkè tí ó wà lọ́hùn-ún yìí ni àwọn baba wa ń sin Ọlọrun, ṣugbọn ẹ̀yin wí pé Jerusalẹmu ni ibi tí a níláti máa sìn ín.” Jesu wí fún un pé, “Arabinrin, gbà mí gbọ́! Àkókò ń bọ̀ tí ó jẹ́ pé, ati ní orí òkè yìí ni, ati ní Jerusalẹmu ni, kò ní sí ibi tí ẹ óo ti máa sin Baba mọ́. Ẹ̀yin ará Samaria kò mọ ẹni tí ẹ̀ ń sìn. Àwa Juu mọ ẹni tí à ń sìn, nítorí láti ọ̀dọ̀ wa ni ìgbàlà ti wá. Ṣugbọn àkókò ń bọ̀, ó tilẹ̀ dé tán báyìí, nígbà tí àwọn tí ń jọ́sìn tòótọ́ yóo máa sin Baba ní ẹ̀mí ati ní òtítọ́, nítorí irú àwọn bẹ́ẹ̀ ni Baba ń wá kí wọ́n máa sin òun. Ẹ̀mí ni Ọlọrun, àwọn tí ó bá ń sìn ín níláti sìn ín ní ẹ̀mí ati ní òtítọ́.” Obinrin náà sọ fún un pé, “Mo mọ̀ pé Mesaya, tí ó ń jẹ́ Kristi, ń bọ̀. Nígbà tí ó bá dé, yóo fi ohun gbogbo hàn wá.” Jesu wí fún un pé, “Èmi tí mò ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí ni Mesaya náà.” Ní àkókò yìí ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dé. Ẹnu yà wọ́n pé obinrin ni ó ń bá sọ̀rọ̀. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni ninu wọn kò bi obinrin náà pé kí ni ó ń wá? Bẹ́ẹ̀ ni wọn kò bi òun náà pé kí ló dé tí ó fi ń bá obinrin sọ̀rọ̀? Obinrin náà fi ìkòkò omi rẹ̀ sílẹ̀, ó lọ sí ààrin ìlú, ó sọ fún àwọn eniyan pé, “Ẹ wá wo ọkunrin tí ó sọ gbogbo ohun tí mo ti ṣe fún mi. Ǹjẹ́ Mesaya tí à ń retí kọ́?” Wọ́n bá jáde láti inú ìlú lọ sọ́dọ̀ Jesu. Lẹ́yìn tí obinrin náà ti lọ sí ààrin ìlú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ń bẹ̀ ẹ́ pé, “Rabi, jẹun.” Ṣugbọn ó dá wọn lóhùn pé, “Mo ní oúnjẹ láti jẹ tí ẹ̀yin kò mọ̀ nípa rẹ̀.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè láàrin ara wọn pé, “Àbí ẹnìkan ti gbé oúnjẹ wá fún un ni?” Jesu wí fún wọn pé, “Ní tèmi, oúnjẹ mi ni láti ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́ ati láti parí iṣẹ́ tí ó fún mi ṣe. Ṣé ẹ máa ń sọ pé, ‘Ìkórè ku oṣù mẹrin.’ Mo sọ fun yín, ẹ gbé ojú yín sókè kí ẹ sì rí i bí oko ti pọ́n fun ìkórè. Ẹni tí ń kórè a máa rí èrè gbà, ó ń kó irè jọ sí ìyè ainipẹkun, kí inú ẹni tí ń fúnrúgbìn ati ti ẹni tí ń kórè lè jọ máa dùn pọ̀. Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí pé, ‘Ọ̀tọ̀ ni ẹni tí ń fúnrúgbìn, ọ̀tọ̀ ni ẹni tí ń kórè.’ Mo ran yín láti kórè níbi tí ẹ kò ti ṣiṣẹ́ ọ̀gbìn. Àwọn ẹnìkan ti ṣiṣẹ́, ẹ̀yin wá ń jèrè iṣẹ́ wọn.” Ọpọlọpọ ninu àwọn ará Samaria tí ó wá láti inú ìlú gbà á gbọ́ nítorí ọ̀rọ̀ obinrin tí ó jẹ́rìí pé, “Ó sọ gbogbo ohun tí mo ṣe fún mi.” Nígbà tí àwọn ará Samaria dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó dúró lọ́dọ̀ wọn. Ó bá dúró níbẹ̀ fún ọjọ́ meji. Ọpọlọpọ àwọn mìíràn tún gbàgbọ́ nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Wọ́n wí fún obinrin náà pé, “Kì í ṣe nítorí ohun tí o sọ ni a fi gbàgbọ́, nítorí àwa fúnra wa ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, a wá mọ̀ nítòótọ́ pé òun ni Olùgbàlà aráyé.” Lẹ́yìn ọjọ́ meji, Jesu jáde kúrò níbẹ̀ lọ sí Galili. Nítorí òun fúnrarẹ̀ jẹ́rìí pé, “Wolii kan kò ní ọlá ninu ìlú baba rẹ̀.” Nígbà tí ó dé Galili, àwọn ará Galili gbà á tọwọ́-tẹsẹ̀, nítorí wọ́n ti rí ohun gbogbo tí ó ti ṣe ní Jerusalẹmu ní àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá, nítorí pé àwọn náà lọ sí ibi àjọ̀dún náà. Jesu tún lọ sí ìlú Kana ti Galili níbi tí ó ti sọ omi di ọtí ní ìjelòó. Ìjòyè kan wà ní Kapanaumu tí ọmọ rẹ̀ ń ṣàìsàn. Nígbà tí ó gbọ́ pé Jesu ti dé sí Galili láti Judia, ó lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti bẹ̀ ẹ́ pé kí ó wá wo ọmọ òun sàn, nítorí ọmọ ọ̀hún ń kú lọ. Jesu wí fún un pé, “Bí ẹ kò bá rí iṣẹ́ àmì ati iṣẹ́ ìyanu ẹ kò ní gbàgbọ́.” Ìjòyè náà bẹ̀ ẹ́ pé, “Alàgbà, tètè wá kí ọmọ mi tó kú.” Jesu wí fún un pé, “Máa lọ, ọmọ rẹ yóo yè.” Ọkunrin náà gba ọ̀rọ̀ tí Jesu sọ fún un gbọ́, ó bá ń lọ sílé. Bí ó ti ń lọ, àwọn iranṣẹ rẹ̀ wá pàdé rẹ̀, wọ́n wí fún un pé, “Ọmọ rẹ ti gbádùn.” Ìjòyè náà wádìí lọ́wọ́ wọn nípa àkókò tí ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí gbádùn. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Lánàá, ní nǹkan bí aago kan ni ibà náà lọ.” Baba ọmọ náà mọ̀ pé àkókò náà gan-an ni Jesu sọ fún òun pé, “Ọmọ rẹ yóo yè.” Òun ati gbogbo ilé rẹ̀ bá gba Jesu gbọ́. Èyí ni iṣẹ́ abàmì keji tí Jesu ṣe nígbà tí ó kúrò ní Judia, tí ó wá sí Galili. Lẹ́yìn èyí, ó tó àkókò fún ọ̀kan ninu àjọ̀dún àwọn Juu: Jesu bá lọ sí Jerusalẹmu. Ẹnu ọ̀nà kan wà ní Jerusalẹmu tí wọn ń pè ní ẹnu ọ̀nà Aguntan. Adágún omi kan wà níbẹ̀ tí ń jẹ́ Betisata ní èdè Heberu. Adágún yìí ní ìloro marun-un tí wọn fi òrùlé bò. Níbẹ̀ ni ọpọlọpọ àwọn aláìsàn ti máa ń jókòó: àwọn afọ́jú, àwọn arọ, ati àwọn tí ó ní àrùn ẹ̀gbà. Wọn a máa retí ìgbà tí omi yóo rú pọ̀; [ nítorí angẹli Oluwa a máa wá lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti rú omi adágún náà pọ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ bọ́ sinu adágún náà lẹ́yìn tí omi náà bá ti rú pọ̀, àìsànkáìsàn tí ó lè máa ṣe é tẹ́lẹ̀, yóo san.] Ọkunrin kan wà níbẹ̀ tí ó ti ń ṣàìsàn fún ọdún mejidinlogoji. Nígbà tí Jesu rí i tí ó dùbúlẹ̀ níbẹ̀, tí ó sì mọ̀ pé ó ti pẹ́ tí ó ti wà níbẹ̀, ó bi í pé, “Ṣé o fẹ́ ìmúláradá?” Aláìsàn náà dáhùn pé, “Alàgbà, n kò ní ẹni tí yóo gbé mi sinu adágún nígbà tí omi bá rú pọ̀, nígbà tí n óo bá fi dé ibẹ̀, ẹlòmíràn á ti wọ inú omi ṣiwaju mi.” Jesu wí fún un pé, “Dìde, ká ẹní rẹ, kí o máa rìn.” Lẹsẹkẹsẹ ara ọkunrin náà dá, ó ká ẹni rẹ̀, ó bá ń rìn. Ọjọ́ náà jẹ́ Ọjọ́ Ìsinmi. Àwọn Juu sọ fún ọkunrin tí ara rẹ̀ ti dá yìí pé, “Ọjọ́ Ìsinmi ni òní! Èèwọ̀ ni pé kí o ru ẹní rẹ!” Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹni tí ó mú mi lára dá ni ó sọ pé kí n ká ẹní mi, kí n máa rìn.” Wọ́n bi í pé, “Ta ni ẹni náà tí ó sọ fún ọ pé kí o ru ẹni, kí o máa rìn?” Ṣugbọn ọkunrin náà tí Jesu wòsàn kò mọ ẹni tí ó wo òun sàn, nítorí pé eniyan pọ̀ níbẹ̀, ati pé Jesu ti yẹra kúrò níbẹ̀. Lẹ́yìn èyí, Jesu rí ọkunrin náà ninu Tẹmpili, ó wí fún un pé, “O rí i pé ara rẹ ti dá nisinsinyii, má dẹ́ṣẹ̀ mọ́ kí ohun tí ó burú ju èyí lọ má baà bá ọ.” Ọkunrin náà pada lọ sọ fún àwọn Juu pé, Jesu ni ẹni tí ó wo òun sàn. Nítorí èyí àwọn Juu dìtẹ̀ sí Jesu, nítorí ó ń ṣe nǹkan wọnyi ní Ọjọ́ Ìsinmi. Ṣugbọn Jesu dá wọn lóhùn pé, “Baba mi ń ṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyìí, èmi náà sì ń ṣiṣẹ́.” Nítorí èyí àwọn Juu túbọ̀ ń wá ọ̀nà láti pa á, nítorí kì í ṣe pé ó ba Ọjọ́ Ìsinmi jẹ́ nìkan ni, ṣugbọn ó pe Ọlọrun ní Baba rẹ̀, ó sọ ara rẹ̀ di ọ̀kan náà pẹlu Ọlọrun. Nígbà náà ni Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, Ọmọ kò lè dá nǹkankan ṣe yàtọ̀ sí ohun tí ó bá rí tí Baba ń ṣe. Àwọn ohun tí Ọmọ rí pé Baba ń ṣe ni òun náà ń ṣe. Nítorí Baba fẹ́ràn Ọmọ rẹ̀, ó sì fi ohun gbogbo tí ó ń ṣe hàn án. Yóo tún fi àwọn iṣẹ́ tí ó tóbi jù wọnyi lọ hàn án, kí ẹnu lè yà yín. Nítorí bí Baba ti ń jí àwọn òkú dìde, tí ó ń sọ wọ́n di alààyè, bẹ́ẹ̀ gan-an ni, ẹnikẹ́ni tí Ọmọ bá fẹ́ ni ó ń sọ di alààyè. Nítorí Baba kò ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni, ṣugbọn ó ti fi gbogbo ìdájọ́ lé Ọmọ lọ́wọ́, kí gbogbo eniyan lè bu ọlá fún Ọmọ bí wọ́n ti ń bu ọlá fún Baba. Ẹni tí kò bá bu ọlá fún Ọmọ kò bu ọlá fún Baba tí ó rán an wá sí ayé. “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó bá gba ẹni tí ó rán mi níṣẹ́ gbọ́, olúwarẹ̀ ní ìyè ainipẹkun, kò ní wá sí ìdájọ́, ṣugbọn ó ti ré ikú kọjá, ó sì ti bọ́ sinu ìyè. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé àkókò ń bọ̀, ó tilẹ̀ dé tán báyìí, tí àwọn òkú yóo gbọ́ ohùn Ọmọ Ọlọrun, àwọn tí ó bá gbọ́ yóo yè. Nítorí bí Baba ti ní ìyè ninu ara rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó ti fún ọmọ ní agbára láti ní ìyè. Ó ti fún un ní àṣẹ láti ṣe ìdájọ́, nítorí òun ni Ọmọ-Eniyan. Ẹ má ṣe jẹ́ kí èyí yà yín lẹ́nu, nítorí àkókò ń bọ̀ nígbà tí gbogbo àwọn òkú tí ó wà ní ibojì yóo gbọ́ ohùn rẹ̀, tí wọn yóo sì jáde. Àwọn tí ó ti ṣe rere yóo jí dìde sí ìyè, àwọn tí ó ti ṣe ibi yóo jí dìde sí ìdálẹ́bi. “Èmi kò lè dá nǹkankan ṣe. Ọ̀rọ̀ Baba mi tí mo bá gbọ́ ni mo fi ń ṣe ìdájọ́, òdodo sì ni ìdájọ́ mi; nítorí kì í ṣe ìfẹ́ tèmi ni mò ń wá bíkòṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́. “Bí ó bá jẹ́ pé èmi ni mò ń jẹ́rìí ara mi, ẹ̀rí mi lè má jẹ́ òtítọ́. Ṣugbọn ẹlòmíràn ni ó ń jẹ́rìí mi, mo sì mọ̀ pé òtítọ́ ni ẹ̀rí tí ó ń jẹ́ nípa mi. Ẹ ti ranṣẹ lọ sọ́dọ̀ Johanu, ó sì ti jẹ́rìí òtítọ́. Kì í ṣe pé dandan ni fún mi pé kí eniyan jẹ́rìí gbè mí. Ṣugbọn mo sọ èyí fun yín kí ẹ lè ní ìgbàlà. Johanu dàbí fìtílà tí ó ń tàn, tí ó sì mọ́lẹ̀. Ó dùn mọ yín fún àkókò díẹ̀ láti máa yọ̀ ninu ìmọ́lẹ̀ tí ó fi fun yín. Ṣugbọn mo ní ẹ̀rí tí ó tóbi ju ti Johanu lọ. Àwọn iṣẹ́ tí Baba ti fún mi pé kí n parí, àní àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe, àwọn ni ẹlẹ́rìí mi pé Baba ni ó rán mi níṣẹ́. Baba tí ó rán mi níṣẹ́ ti jẹ́rìí mi. Ẹnikẹ́ni kò ì tíì gbọ́ ohùn rẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò rí i bí ó ti rí rí. Ẹ kò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbé inú yín nítorí ẹ kò gba ẹni tí ó rán níṣẹ́ gbọ́. Ẹ̀ ń wá inú Ìwé Mímọ́ káàkiri nítorí pé ẹ rò pé ẹ óo rí ọ̀rọ̀ ìyè ainipẹkun ninu rẹ̀. Ẹ̀rí mi gan-an ni wọ́n sì ń jẹ́. Sibẹ ẹ kò fẹ́ tọ̀ mí wá kí ẹ lè ní ìyè. “Èmi kò wá ọlá láti ọ̀dọ̀ eniyan. Ṣugbọn mo mọ̀ yín, mo sì mọ̀ pé ẹ kò ní ìfẹ́ Ọlọrun ninu yín. Èmi wá ní orúkọ Baba mi, ẹ̀yin kò gbà mí. Ṣugbọn bí ẹlòmíràn bá wá ní orúkọ ara rẹ̀, ẹ óo gbà á. Báwo ni ẹ ti ṣe lè gbàgbọ́ nígbà tí ó jẹ́ pé láàrin ara yín ni ẹ ti ń gba ọlá, tí ẹ kò wá ọlá ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun nìkan ṣoṣo? Ẹ má ṣe rò pé èmi ni n óo fi yín sùn níwájú Baba, Mose tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé gan-an ni yóo fi yín sùn. Bí ẹ bá gba Mose gbọ́, ẹ̀ bá gbà mí gbọ́, nítorí èmi ni ọ̀rọ̀ ìwé tí ó kọ bá wí. Ṣugbọn bí ẹ kò bá gba ohun tí ó kọ gbọ́, báwo ni ẹ óo ti ṣe gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́?” Lẹ́yìn èyí, Jesu lọ sí òdìkejì òkun Galili tí ó tún ń jẹ́ òkun Tiberiasi. Ọ̀pọ̀ eniyan ń tẹ̀lé e nítorí wọ́n rí iṣẹ́ ìyanu tí ó ń ṣe lára àwọn aláìsàn. Jesu bá gun orí òkè lọ, ó jókòó níbẹ̀ pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá, tíí ṣe àjọ̀dún pataki láàrin àwọn Juu. Nígbà tí Jesu gbé ojú sókè, ó rí ọ̀pọ̀ eniyan tí ó wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó wá bi Filipi pé, “Níbo ni a ti lè ra oúnjẹ fún àwọn eniyan yìí láti jẹ?” Ó fi èyí wá Filipi lẹ́nu wò ni, nítorí òun fúnrarẹ̀ ti mọ ohun tí òun yóo ṣe. Filipi dá a lóhùn pé, “Burẹdi igba owó fadaka kò tó kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn lè fi rí díẹ̀díẹ̀ panu!” Nígbà náà ni Anderu, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tí ó jẹ́ arakunrin Simoni Peteru sọ fún un pé, “Ọdọmọkunrin kan wà níhìn-ín tí ó ní burẹdi bali marun-un ati ẹja meji, ṣugbọn níbo ni èyí dé láàrin ogunlọ́gọ̀ eniyan yìí?” Jesu ní, “Ẹ ní kí wọ́n jókòó.” Koríko pọ̀ níbẹ̀. Àwọn eniyan náà bá jókòó. Wọ́n tó bí ẹgbẹẹdọgbọn (5,000). Jesu wá mú burẹdi náà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó bá pín in fún àwọn eniyan tí ó jókòó. Bákan náà ni ó ṣe sí ẹja, ó fún olukuluku bí ó ti ń fẹ́. Lẹ́yìn tí àwọn eniyan ti jẹ ẹja ní àjẹtẹ́rùn, Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ kó oúnjẹ tí ó kù jọ, kí ohunkohun má baà ṣòfò.” Wọ́n bá kó o jọ. Àjẹkù burẹdi marun-un náà kún agbọ̀n mejila, lẹ́yìn tí àwọn eniyan ti jẹ tán. Nígbà tí àwọn eniyan rí iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe, wọ́n ní, “Dájúdájú, eléyìí ni wolii Ọlọrun náà tí ó ń bọ̀ wá sí ayé.” Nígbà tí Jesu mọ̀ pé wọn ń fẹ́ wá fi ipá mú òun kí wọ́n sì fi òun jọba, ó yẹra kúrò níbẹ̀, òun nìkan tún pada lọ sórí òkè. Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí èbúté, wọ́n wọ ọkọ̀, wọ́n ń lọ sí Kapanaumu ní òdìkejì òkun. Òkùnkùn ti ṣú ṣugbọn Jesu kò ì tíì dé ọ̀dọ̀ wọn. Ni omi òkun bá bẹ̀rẹ̀ sí ru sókè nítorí afẹ́fẹ́ líle ń fẹ́. Lẹ́yìn tí wọ́n ti wa ọkọ̀ bí ibùsọ̀ mẹta tabi mẹrin wọ́n rí Jesu, ó ń rìn lórí òkun, ó ti súnmọ́ etí ọkọ̀ wọn. Ẹ̀rù bà wọ́n. Ṣugbọn ó wí fún wọn pé, “Èmi ni. Ẹ má bẹ̀rù.” Wọ́n bá fi tayọ̀tayọ̀ gbà á sinu ọkọ̀. Lẹsẹkẹsẹ ọkọ̀ sì gúnlẹ̀ sí ibi tí wọn ń lọ. Ní ọjọ́ keji, àwọn tí wọ́n dúró ní òdìkejì òkun rí i pé ọkọ̀ kanṣoṣo ni ó wà níbẹ̀. Wọ́n tún wòye pé Jesu kò bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ọkọ̀; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nìkan ni wọ́n lọ. Ṣugbọn àwọn ọkọ̀ mìíràn wá láti Tiberiasi lẹ́bàá ibi tí àwọn eniyan ti jẹun lẹ́yìn tí Oluwa ti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun. Nígbà tí àwọn eniyan rí i pé Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kò sí níbẹ̀, àwọn náà bọ́ sinu àwọn ọkọ̀ tí ó wà níbẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tọpa Jesu lọ sí Kapanaumu. Nígbà tí wọ́n rí i ní òdìkejì òkun, wọ́n bi í pé, “Olùkọ́ni, nígbà wo ni o ti dé ìhín?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, kì í ṣe nítorí pé ẹ rí iṣẹ́ ìyanu mi ni ẹ ṣe ń wá mi, ṣugbọn nítorí ẹ jẹ oúnjẹ àjẹyó ni. Ẹ má ṣe làálàá nítorí oúnjẹ ti yóo bàjẹ́, ṣugbọn ẹ ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tí ọmọ eniyan yóo fun yín, tí yóo wà títí di ìyè ainipẹkun, nítorí ọmọ eniyan ni Ọlọrun Baba fún ní àṣẹ.” Wọ́n wá bi í pé, “Kí ni kí á ṣe kí á lè máa ṣe iṣẹ́ Ọlọrun?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Iṣẹ́ Ọlọrun ni pé kí ẹ gba ẹni tí ó rán gbọ́.” Wọ́n wá bi í pé, “Iṣẹ́ ìyanu wo ni ìwọ óo ṣe, tí a óo rí i, kí á lè gbà ọ́ gbọ́? Iṣẹ́ wo ni o óo ṣe? Àwọn baba wa jẹ mana ní aṣálẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, ‘Ó fún wọn ní oúnjẹ láti ọ̀run wá jẹ.’ ” Jesu wí fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, kì í ṣe Mose ni ó fun yín ní oúnjẹ láti ọ̀run wá. Baba mi ni ó ń fun yín ní oúnjẹ láti ọ̀run wá; nítorí oúnjẹ Ọlọrun ni ẹni tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, tí ó ń fi ìyè fún aráyé.” Wọ́n bá sọ fún un pé, “Alàgbà, máa fún wa ní oúnjẹ yìí nígbà gbogbo.” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi gan-an ni oúnjẹ tí ń fún eniyan ní ìyè, ẹni tí ó bá wá sọ́dọ̀ mi, ebi kò ní pa á, ẹni tí ó bá sì gbà mí gbọ́, òùngbẹ kò ní gbẹ ẹ́ laelae. Ṣugbọn mo wí fun yín pé ẹ̀yin ti rí mi, sibẹ ẹ kò gbàgbọ́. Gbogbo ẹni tí Baba ti fi fún mi yóo wá sọ́dọ̀ mi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá sọ́dọ̀ mi, n kò ní ta á nù; nítorí pé mo sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, kì í ṣe láti ṣe ìfẹ́ ti ara mi, bíkòṣe láti ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́. Èyí ni ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́, pé kí n má ṣe sọ ẹnikẹ́ni nù ninu àwọn tí ó fi fún mi, ṣugbọn kí n jí wọn dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn. Nítorí ìfẹ́ Baba mi ni pé, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí Ọmọ rẹ̀, tí ó bá gbà á gbọ́, lè ní ìyè ainipẹkun. Èmi fúnra mi yóo jí wọn dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn.” Àwọn Juu wá bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí i nítorí ó wí pé, “Èmi gan-an ni oúnjẹ tí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá.” Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé, “Ṣebí Jesu ọmọ Josẹfu ni; ẹni tí a mọ baba ati ìyá rẹ̀? Ó ṣe wá sọ pé, láti ọ̀run ni òun ti sọ̀kalẹ̀ wá?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má ṣe kùn láàrin ara yín mọ́. Kò sí ẹni tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi àfi bí Baba tí ó rán mi níṣẹ́ bá fà á wá, èmi óo wá jí i dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn. Ó wà ní àkọsílẹ̀ ninu ìwé àwọn wolii pé, ‘Gbogbo wọn ni Ọlọrun yóo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́.’ Gbogbo ẹni tí ó bá gba ọ̀rọ̀ Baba, tí ó kọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀, á wá sọ́dọ̀ mi. Kò sí ẹni tí ó rí Baba rí àfi ẹni tí ó ti wà pẹlu Baba ni ó ti rí Baba. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹni tí ó bá gbàgbọ́ ní ìyè ainipẹkun. Èmi pàápàá ni oúnjẹ tí ó ń fún eniyan ní ìyè. Àwọn baba wa jẹ mana ní aṣálẹ̀, sibẹ wọ́n kú. Ṣugbọn oúnjẹ tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ ni èyí tí ó jẹ́ pé bí ẹnìkan bá jẹ ninu rẹ̀, olúwarẹ̀ kò ní kú. Èmi ni oúnjẹ tí ó wà láàyè tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀. Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ninu oúnjẹ yìí, olúwarẹ̀ yóo wà láàyè laelae. Oúnjẹ tí èmi yóo fi fún un ni ẹran ara mi tí yóo fi ìyè fún gbogbo ayé.” Gbolohun yìí dá àríyànjiyàn sílẹ̀ láàrin àwọn Juu. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bi ara wọn pé, “Báwo ni eléyìí ti ṣe lè fún wa ní ẹran-ara rẹ̀ jẹ?” Jesu wá wí fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, bí ẹ̀yin kò bá jẹ ẹran ara ọmọ eniyan, kí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ kò lè ní ìyè ninu yín. Ẹni tí ó bá jẹ ẹran-ara mi, tí ó sì mu ẹ̀jẹ̀ mi, ní ìyè ainipẹkun, èmi yóo sì jí i dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn. Ẹran-ara mi ni oúnjẹ gidi, ẹ̀jẹ̀ mi sì ni ohun mímu iyebíye. Ẹni tí ó bá jẹ ẹran-ara mi, tí ó sì mu ẹ̀jẹ̀ mi, olúwarẹ̀ ń gbé inú mi, èmi náà sì ń gbé inú rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Baba alààyè ti rán mi, bẹ́ẹ̀ ni mo wà láàyè nítorí ti Baba. Ẹni tí ó bá jẹ ẹran ara mi, yóo yè nítorí tèmi. Èyí ni oúnjẹ tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀, kì í ṣe irú èyí tí àwọn baba yín jẹ, tí wọ́n sì kú sibẹsibẹ. Ẹni tí ó bá jẹ oúnjẹ yìí yóo wà láàyè laelae.” Jesu sọ ọ̀rọ̀ yìí nígbà tí ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu ilé ìpàdé wọn ní Kapanaumu. Ọpọlọpọ tí ó gbọ́ ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ pé, “Ọ̀rọ̀ yìí le, kò sí ẹni tí ó lè gba irú rẹ̀!” Nígbà tí Jesu rí i pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń kùn nítorí rẹ̀, ó bi wọ́n pé, “Ṣé ọ̀rọ̀ yìí ni ó mú kí ọkàn yín dààmú? Tí ẹ bá wá rí Ọmọ-Eniyan tí ń gòkè lọ sí ibi tí ó wà tẹ́lẹ̀ ńkọ́? Ẹ̀mí ní ń sọ eniyan di alààyè, ẹran-ara kò ṣe anfaani kankan. Ọ̀rọ̀ tí mo ti ba yín sọ jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀mí ati ti ìyè. Ṣugbọn àwọn tí kò gbàgbọ́ wà ninu yín.” Jesu sọ èyí nítorí láti ìbẹ̀rẹ̀ ni ó ti mọ àwọn tí kò gbàgbọ́ ati ẹni tí yóo fi òun lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́. Ó ní, “Nítorí èyí ni mo ṣe sọ fun yín pé kò sí ẹni tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi, àfi bí Baba mi bá ṣí ọ̀nà fún un láti wá.” Nítorí èyí, ọpọlọpọ ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pada lẹ́yìn rẹ̀, wọn kò tún bá a rìn mọ́. Jesu bá bi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila pé, “Ẹ̀yin náà fẹ́ lọ bí?” Simoni Peteru dá a lóhùn pé, “Oluwa, ọ̀dọ̀ ta ni à bá lọ? Ìwọ ni o ní ọ̀rọ̀ ìyè ainipẹkun. Ní tiwa, a ti gbàgbọ́, a sì ti mọ̀ pé ìwọ ni Ẹni Mímọ́ Ọlọrun.” Jesu bá sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ̀yin mejila ni mo yàn. Ṣugbọn ẹni ibi ni ọ̀kan ninu yín.” Ó wí èyí nípa Judasi Iskariotu ọmọ Simoni, nítorí òun ni ẹni tí yóo fi í lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́. Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila ni Judasi Iskariotu yìí. Lẹ́yìn èyí, Jesu ń lọ káàkiri ní ilẹ̀ Galili nítorí kò fẹ́ máa káàkiri ilẹ̀ Judia mọ́, nítorí àwọn Juu ń wá ọ̀nà láti pa á. Ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò àjọ̀dún àwọn Juu nígbà tí wọn ń ṣe Àjọ̀dún Ìpàgọ́ ní aṣálẹ̀. Àwọn arakunrin Jesu sọ fún un pé, “Kúrò níhìn-ín kí o lọ sí Judia, kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ lè rí iṣẹ́ tí ò ń ṣe, nítorí kò sí ẹni tíí fi ohun tí ó bá ń ṣe pamọ́, bí ó bá fẹ́ kí àwọn eniyan mọ òun. Tí o bá ń ṣe nǹkan wọnyi, fi ara rẹ han aráyé.” (Àwọn arakunrin rẹ̀ kò gbà á gbọ́ ni wọ́n ṣe sọ bẹ́ẹ̀.) Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àkókò tí ó wọ̀ fún mi kò ì tíì tó, ìgbà gbogbo ni ó wọ̀ fún ẹ̀yin. Ayé kò lè kórìíra yín, èmi ni wọ́n kórìíra, nítorí ẹ̀rí mi lòdì sí wọn nítorí pé iṣẹ́ wọn burú. Ẹ̀yin ẹ máa lọ sí ibi àjọ̀dún, èmi kò ní lọ sí ibi àjọ̀dún yìí nítorí àkókò tí ó wọ̀ fún mi kò ì tíì tó.” Nígbà tí ó wí báyìí tán, ó tún dúró ní ilẹ̀ Galili. Lẹ́yìn tí àwọn arakunrin Jesu ti lọ sí ibi àjọ̀dún náà, òun náà wá lọ. Ṣugbọn, kò lọ ní gbangba, yíyọ́ ni ó yọ́ lọ. Àwọn Juu bẹ̀rẹ̀ sí wá a níbi àjọ̀dún náà, wọ́n ń bèèrè pé, “Níbo ni ó wà?” Oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ ni àwọn eniyan ń sọ nípa rẹ̀. Àwọn kan ń sọ pé, “Eniyan rere ni.” Ṣugbọn àwọn mìíràn ń sọ pé, “Rárá o, ó ń tan àwọn eniyan jẹ ni.” Ṣugbọn wọn kò sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní gbangba nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn Juu. Nígbà tí àjọ̀dún ti fẹ́rẹ̀ kọjá ìdajì, Jesu lọ sí Tẹmpili, ó ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́. Ẹnu ya àwọn Juu, wọ́n ń sọ pé, “Báwo ni eléyìí ti ṣe mọ ìwé tó báyìí nígbà tí kò lọ sí ilé-ìwé?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀kọ́ tèmi kì í ṣe ti ara mi, ti ẹni tí ó rán mi níṣẹ́ ni. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọrun, olúwarẹ̀ yóo mọ̀ bí ẹ̀kọ́ yìí bá jẹ́ ti Ọlọrun, tabi bí ó bá jẹ́ pé ti ara mi ni mò ń sọ. Ẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ti ara rẹ̀ ń wá ògo ti ara rẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí ó bá ń wá ògo ẹni tí ó rán an níṣẹ́ jẹ́ olóòótọ́, kò sí aiṣododo ninu rẹ̀. Mo ṣebí Mose ti fun yín ní Òfin? Sibẹ kò sí ẹnìkan ninu yín tí ó ń ṣe ohun tí òfin wí. Nítorí kí ni ẹ ṣe ń wá ọ̀nà láti pa mí?” Àwọn eniyan dá a lóhùn pé, “Nǹkan kọ lù ọ́! Ta ni ń wá ọ̀nà láti pa ọ́?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo ṣe iṣẹ́ kan, ẹnu ya gbogbo yín. Nítorí pé Mose fun yín ní òfin ìkọlà, ẹ̀ ń kọlà fún eniyan ní Ọjọ́ Ìsinmi. Ṣugbọn òfin yìí kò bẹ̀rẹ̀ pẹlu Mose, àwọn baba-ńlá wa ni ó dá a sílẹ̀. Ẹ̀yin ń kọ ilà ní Ọjọ́ Ìsinmi kí ẹ má baà rú òfin Mose, ẹ wá ń bínú sí mi nítorí mo wo eniyan sàn ní Ọjọ́ Ìsinmi! Ẹ má wo ojú eniyan ṣe ìdájọ́, ṣugbọn ẹ máa ṣe ìdájọ́ ẹ̀tọ́.” Àwọn kan ninu àwọn ará Jerusalẹmu bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé, “Ẹni tí wọ́n fẹ́ pa kọ́ yìí? Wò ó bí ó ti ń sọ̀rọ̀ ní gbangba tí wọn kò sì sọ ohunkohun sí i. Àbí àwọn aláṣẹ ti mọ̀ dájú pé òun ni Mesaya ni? Ṣugbọn eléyìí kò lè jẹ́ Mesaya, nítorí a mọ ibi tí ó ti wá. Nígbà tí Mesaya bá dé, ẹnikẹ́ni kò ní mọ ibi tí ó ti wá.” Ni Jesu bá kígbe sókè bí ó ti ń kọ́ àwọn eniyan ninu Tẹmpili. Ó ní, “Òtítọ́ ni pe ẹ mọ̀ mí, ẹ sì mọ ibi tí mo ti wá. Ṣugbọn kì í ṣe èmi ni mo rán ara mi wá, olóòótọ́ ni ẹni tí ó rán mi, tí ẹ̀yin kò mọ̀. Èmi mọ̀ ọ́n, nítorí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni mo ti wá, òun ni ó sì rán mi níṣẹ́.” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí wá ọ̀nà láti mú un, ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò fi ọwọ́ kàn án nítorí àkókò rẹ̀ kò ì tíì tó. Ọpọlọpọ ninu àwọn eniyan gbà á gbọ́, wọ́n ń sọ pé, “Bí Mesaya náà bá dé, ǹjẹ́ yóo ṣe iṣẹ́ ìyanu ju èyí tí ọkunrin yìí ń ṣe lọ?” Àwọn Farisi gbọ́ pé àwọn eniyan ń sọ ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ báyìí láàrin ara wọn nípa Jesu. Àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi wá rán àwọn ẹ̀ṣọ́ Tẹmpili pé kí wọ́n lọ mú Jesu wá. Jesu bá dáhùn pé, “Àkókò díẹ̀ ni ó kù tí n óo lò pẹlu yín, lẹ́yìn náà n óo lọ sọ́dọ̀ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́. Ẹ óo wá mi, ẹ kò ní rí mi, ibi tí mo bá wà, ẹ kò ní lè dé ibẹ̀.” Àwọn Juu bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Níbo ni ọkunrin yìí yóo lọ tí àwa kò fi ní rí i? Àbí ó ha fẹ́ lọ sí ààrin àwọn ará wa tí ó fọ́nká sí ààrin àwọn Giriki ni? Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí tí ó sọ pé, ‘Ẹ óo wá mi, ẹ kò ní rí mi, níbi tí mo bá wà, ẹ kò ní lè dé ibẹ̀?’ ” Nígbà tí ó di ọjọ́ tíí àjọ̀dún yóo parí, tíí ṣe ọjọ́ tí ó ṣe pataki jùlọ, Jesu dìde dúró, ó kígbe pé, “Bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹnikẹ́ni, kí ó wá sọ́dọ̀ mi kí ó mu omi. Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, láti inú rẹ̀ ni odò omi ìyè yóo ti máa sun jáde, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí.” Ó wí èyí nípa Ẹ̀mí tí àwọn tí ó gbà á gbọ́ yóo gbà láì pẹ́, nítorí nígbà náà ẹnikẹ́ni kò ì tíì rí ẹ̀bùn Ẹ̀mí gbà nítorí a kò ì tíì ṣe Jesu lógo. Ninu àwọn tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, àwọn kan ń sọ pé, “Òun ni wolii tí à ń retí nítòótọ́.” Àwọn mìíràn ń sọ pé, “Òun ni Mesaya.” Ṣugbọn àwọn mìíràn ń sọ pé, “Báwo ni Mesaya ti ṣe lè wá láti Galili? Ṣebí Ìwé Mímọ́ ti sọ pé láti inú ìdílé Dafidi, ní Bẹtilẹhẹmu ìlú Dafidi, ni Mesaya yóo ti wá?” Ni ìyapa bá bẹ́ sáàrin àwọn eniyan nítorí rẹ̀. Àwọn kan ninu wọn fẹ́ mú un, ṣugbọn kò sí ẹni tí ó fi ọwọ́ kàn án. Nígbà tí àwọn ẹ̀ṣọ́ Tẹmpili tí wọ́n rán lọ mú Jesu pada dé ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi, wọ́n bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ kò fi mú un wá?” Àwọn ẹ̀ṣọ́ ọ̀hún bá dáhùn pé, “Ẹnikẹ́ni kò sọ̀rọ̀ bí ọkunrin yìí rí!” Àwọn Farisi bá bi wọ́n pé, “Àbí ẹ̀yin náà ti di ara àwọn tí ó ń tàn jẹ? Ṣé kò ṣá sí ẹnikẹ́ni ninu àwọn aláṣẹ ati àwọn Farisi tí ó gbà á gbọ́? A ti fi àwọn eniyan wọnyi tí kò mọ Òfin Mose gégùn-ún!” Ọ̀kan ninu àwọn Farisi ọ̀hún ni Nikodemu, ẹni tí ó lọ sọ́dọ̀ Jesu nígbà kan. Ó bi wọ́n léèrè pé, “Ǹjẹ́ òfin wa dá eniyan lẹ́bi láìjẹ́ pé a kọ́ gbọ́ ti ẹnu rẹ̀, kí á mọ ohun tí ó ṣe?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àbí ará Galili ni ìwọ náà? Lọ wádìí kí o rí i pé wolii kankan kò lè ti Galili wá!” [ Ni olukuluku wọn bá lọ sí ilé wọn; ṣugbọn Jesu lọ sí Òkè Olifi. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ó tún lọ sí Tẹmpili. Gbogbo àwọn eniyan ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó bá jókòó, ó ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Àwọn amòfin ati àwọn Farisi mú obinrin kan wá, tí wọ́n ká mọ́ ibi tí ó ti ń ṣe àgbèrè. Wọ́n ní kí ó dúró láàrin wọn; wọ́n wá sọ fún Jesu pé, “Olùkọ́ni, a ká obinrin yìí mọ́ ibi tí ó ti ń ṣe àgbèrè, a ká a mọ́ ọn gan-an ni! Ninu Òfin wa Mose pàṣẹ pé kí á sọ irú àwọn bẹ́ẹ̀ ní òkúta pa. Kí ni ìwọ wí?” Wọ́n sọ èyí láti fi ká ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu ni kí wọ́n lè fi ẹ̀sùn kàn án. Jesu bá bẹ̀rẹ̀, ó ń fi ìka kọ nǹkan sórí ilẹ̀. Bí wọ́n ti dúró tí wọ́n tún ń bi í, ó gbé ojú sókè ní ìjókòó tí ó wà, ó wí fún wọn pé, “Ẹni tí kò bá ní ẹ̀ṣẹ̀ ninu yín ni kí ó kọ́ sọ ọ́ ní òkúta.” Ó bá tún bẹ̀rẹ̀, ó ń fi ìka kọ nǹkan sórí ilẹ̀. Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lọ lọ́kọ̀ọ̀kan, àwọn àgbààgbà ni wọ́n kọ́ lọ. Gbogbo wọ́n bá túká pátá láìku ẹnìkan. Ó wá ku obinrin yìí nìkan níbi tí ó dúró sí. Nígbà tí Jesu gbé ojú sókè, ó bi obinrin náà pé, “Obinrin, àwọn dà? Ẹnìkan ninu wọn kò dá ọ lẹ́bi?” Ó ní, “Alàgbà, ẹnìkankan kò dá mi lẹ́bi.” Jesu wí fún un pé, “Èmi náà kò dá ọ lẹ́bi. Máa lọ; láti ìsinsìnyìí lọ, má ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́.”] Jesu tún wí fún wọn pé, “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ẹni tí ó bá ń tẹ̀lé mi kò ní rìn ninu òkùnkùn, ṣugbọn yóo wá sinu ìmọ́lẹ̀ ìyè.” Àwọn Farisi sọ fún un pé, “Ò ń jẹ́rìí ara rẹ, ẹ̀rí rẹ kò jámọ́ nǹkankan.” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Bí mo bá ń jẹ́rìí ara mi, sibẹ òtítọ́ ni ẹ̀rí mi, nítorí mo mọ ibi tí mo ti wá, mo sì mọ ibi tí mò ń lọ. Ṣugbọn ẹ̀yin kò mọ ibi tí mo ti wá, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì mọ ibi tí mò ń lọ. Ojú ni ẹ̀ ń wò tí ẹ fi ń ṣe ìdájọ́, èmi kò ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni. Bí mo bá tilẹ̀ ṣe ìdájọ́, òtítọ́ ni ìdájọ́ mi, nítorí kì í ṣe èmi nìkan ni mò ń ṣe ìdájọ́, èmi ati Baba tí ó rán mi níṣẹ́ ni. Ninu òfin yín a kọ ọ́ pé òtítọ́ ni ẹ̀rí ẹni meji. Èmi fúnra mi jẹ́rìí ara mi, Baba tí ó rán mi níṣẹ́ náà sì ń jẹ́rìí mi.” Wọ́n bi í pé, “Níbo ni baba rẹ wà?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ kò mọ̀ mí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mọ Baba mi. Bí ó bá jẹ́ pé ẹ mọ̀ mí, ẹ̀ bá mọ Baba mi.” Jesu wí báyìí nígbà tí ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu Tẹmpili ninu iyàrá ìṣúra. Ẹnikẹ́ni kò mú un, nítorí àkókò rẹ̀ kò ì tíì tó. Jesu tún wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ ní tèmi; ẹ óo máa wá mi kiri, ẹ óo sì kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ yín. Ẹ kò ní lè dé ibi tí mò ń lọ.” Àwọn Juu bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé, “Kò ṣá ní pa ara rẹ̀, nítorí ó wí pé, ‘Ẹ kò ní lè dé ibi tí mò ń lọ.’ ” Ó wá wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin, ní tiyín, ìsàlẹ̀ ni ẹ ti wá, ṣugbọn ní tèmi, òkè ọ̀run ni mo ti wá. Ti ayé yìí ni yín, èmi kì í ṣe ti ayé yìí. Nítorí náà, mo wí fun yín pé ẹ óo kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ yín. Nítorí bí ẹ kò bá gbàgbọ́ pé, ‘Èmi ni,’ ẹ óo kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ yín.” Wọ́n bi í pé, “Ta ni ọ́?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo ti sọ ẹni tí mo jẹ́ fun yín láti ìbẹ̀rẹ̀. Mo ní ohun pupọ láti sọ nípa yín ati láti fi ṣe ìdájọ́ yín. Olóòótọ́ ni ẹni tí ó rán mi níṣẹ́; ohun tí mo gbọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀ ni mò ń sọ fún aráyé.” Wọn kò mọ̀ pé ọ̀rọ̀ Baba ni ó ń sọ fún wọn. Jesu tún wí fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ bá gbé Ọmọ-Eniyan sókè, nígbà náà ni ẹ óo mọ̀ pé èmi ni, ati pé èmi kò dá ohunkohun ṣe fúnra mi, ṣugbọn bí Baba ti kọ́ mi ni mò ń sọ̀rọ̀ yìí. Ẹni tí ó rán mi níṣẹ́ wà pẹlu mi, kò fi mí sílẹ̀ ní èmi nìkan, nítorí mò ń ṣe ohun tí ó wù ú nígbà gbogbo.” Nígbà tí Jesu sọ ọ̀rọ̀ báyìí, ọpọlọpọ eniyan gbà á gbọ́. Jesu bá wí fún àwọn Juu tí ó gbà á gbọ́ pé, “Bí ẹ̀yin bá ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ mi, ọmọ-ẹ̀yìn mi ni yín nítòótọ́; ẹ óo mọ òtítọ́, òtítọ́ yóo sì sọ yín di òmìnira.” Wọ́n sọ fún un pé, “Ìran Abrahamu ni wá, a kò fi ìgbà kan jẹ́ ẹrú ẹnikẹ́ni. Kí ni ìtumọ̀ gbolohun tí o wí pé, ‘Ẹ̀yin yóo di òmìnira’?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni. Ẹrú kì í gbé inú ilé títí, ọmọ níí gbé inú ilé títí. Nítorí náà, bí Ọmọ bá sọ yín di òmìnira, ẹ óo di òmìnira nítòótọ́. Mo mọ̀ pé ìran Abrahamu ni yín, sibẹ ẹ̀ ń wá ọ̀nà láti pa mí, nítorí ọ̀rọ̀ mi kò rí àyè ninu yín. Ohun tí èmi ti rí lọ́dọ̀ Baba mi ni mò ń sọ, ohun tí ẹ̀yin ti gbọ́ lọ́dọ̀ baba yín ni ẹ̀ ń ṣe.” Wọ́n sọ fún un pé, “Abrahamu ni baba wa.” Jesu wí fún wọn pé, “Bí ó bá jẹ́ pé ọmọ Abrahamu ni yín, irú ohun tí Abrahamu ṣe ni ẹ̀ bá máa ṣe. Ṣugbọn ẹ̀yin ń wá ọ̀nà láti pa mí, bẹ́ẹ̀ sì ni òtítọ́ tí mo gbọ́ lọ́dọ̀ Ọlọrun ni mo sọ fun yín. Abrahamu kò hu irú ìwà bẹ́ẹ̀. Irú ohun tí baba yín ṣe ni ẹ̀ ń ṣe.” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwa kì í ṣe ọmọ àlè, baba kan ni a ní, òun náà sì ni Ọlọrun.” Jesu wí fún wọn pé, “Ìbá jẹ́ pé Ọlọrun ni baba yín, ẹ̀ bá fẹ́ràn mi, nítorí ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni mo ti wá. Nítorí kì í ṣe èmi ni mo rán ara mi wá, ṣugbọn òun ni ó rán mi. Nítorí kí ni ohun tí mò ń sọ fun yín kò fi ye yín? Ìdí rẹ̀ ni pé ara yín kò lè gba ọ̀rọ̀ mi. Láti ọ̀dọ̀ èṣù baba yín, ni ẹ ti wá. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ baba yín ni ẹ ń fẹ́ ṣe. Òun ní tirẹ̀, apànìyàn ni láti ìbẹ̀rẹ̀, ara rẹ̀ kọ òtítọ́ nítorí kò sí òtítọ́ ninu rẹ̀. Nígbà tí ó bá sọ̀rọ̀, irọ́ ni ó ń pa. Ọ̀rọ̀ ti ara rẹ̀ ní ń sọ. Òpùrọ́ ni, òun sì ni baba irọ́. Ṣugbọn nítorí pe òtítọ́ ni mò ń sọ, ẹ kò gbà mí gbọ́. Ta ni ninu yín tí ó ká ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ mi lọ́wọ́ rí? Bí mo bá ń sọ òtítọ́, kí ló dé tí ẹ kò fi gbà mí gbọ́? Ẹni tí ó bá jẹ́ ti Ọlọrun yóo gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ìdí tí ẹ kò fi gbọ́ ni èyí, nítorí ẹ kì í ṣe ẹni Ọlọrun.” Àwọn Juu sọ fún un pé, “A kúkú ti sọ pé ará Samaria ni ọ́, ati pé o ní ẹ̀mí èṣù!” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi kò ní ẹ̀mí èṣù rárá! Èmi ń bu ọlá fún Baba mi, ṣugbọn ẹ̀yin ń bu ẹ̀tẹ́ lù mí. Èmi kò wá ògo ti ara mi, ẹnìkan wà tí ó ń wá ògo mi, òun ni ó ń ṣe ìdájọ́. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé bí ẹnikẹ́ni bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kò ní kú laelae.” Àwọn Juu wá sọ fún un pé, “A wá mọ̀ dájú pé o ní ẹ̀mí èṣù wàyí! Abrahamu kú. Àwọn wolii kú. Ìwọ wá ń sọ pé, ‘Bí ẹnikẹ́ni bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kò ní tọ́ ikú wò laelae.’ Abrahamu baba wa, tí ó ti kú ńkọ́? Ṣé ìwọ jù ú lọ ni? Ati àwọn wolii tí wọ́n ti kú? Ta ni o tilẹ̀ ń fi ara rẹ pè?” Jesu dáhùn pé, “Bí mo bá bu ọlá fún ara mi, òfo ni ọlá mi. Baba mi ni ó bu ọlá fún mi, òun ni ẹ̀yin ń pè ní Ọlọrun yín. Ẹ kò mọ̀ ọ́n, ṣugbọn èmi mọ̀ ọ́n. Bí mo bá sọ pé èmi kò mọ̀ ọ́n, èmi yóo di òpùrọ́ bíi yín. Ṣugbọn mo mọ̀ ọ́n, mo sì ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́. Inú Abrahamu baba yín dùn láti rí àkókò wíwá mi, ó rí i, ó sì yọ̀.” Àwọn Juu sọ fún un pé, “Ìwọ yìí ti rí Abrahamu, nígbà tí o kò ì tíì tó ẹni aadọta ọdún?” Jesu wí fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, kí wọ́n tó bí Abrahamu ni èmi ti wà.” Wọ́n bá ṣa òkúta, wọ́n fẹ́ sọ ọ́ lù ú, ṣugbọn ó fi ara pamọ́, ó bá kúrò ninu Tẹmpili. Bí Jesu ti ń kọjá lọ, ó rí ọkunrin kan tí ó fọ́jú láti inú ìyá rẹ̀ wá. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bi í pé, “Olùkọ́ni, ta ni ó dẹ́ṣẹ̀, ọkunrin yìí ni, tabi àwọn òbí rẹ̀, tí wọ́n fi bí i ní afọ́jú?” Jesu dáhùn pé, “Ati òun ni, ati àwọn òbí rẹ̀ ni, kò sí ẹni tí ó dẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn kí iṣẹ́ Ọlọrun lè hàn nípa ìwòsàn rẹ̀ ni. Dandan ni fún mi kí n ṣe iṣẹ́ ẹni tí ó rán mi ní ojúmọmọ, ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ ṣú ná, tí ẹnikẹ́ni kò ní lè ṣiṣẹ́. Níwọ̀n ìgbà tí mo wà ní ayé, èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.” Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, ó tutọ́ sílẹ̀, ó fi po amọ̀, ó bá fi lẹ ojú ọkunrin náà. Ó wí fún un pé, “Lọ bọ́jú ninu adágún tí ó ń jẹ́ Siloamu.” (Ìtumọ̀ Siloamu ni “rán níṣẹ́.”) Ọkunrin náà lọ, ó bọ́jú, ó bá ríran. Nígbà tí àwọn aládùúgbò rẹ̀ ati àwọn tí wọn máa ń rí i tẹ́lẹ̀ tí ó máa ń ṣagbe, rí i, wọ́n ń bi ara wọn pé, “Ǹjẹ́ ọkunrin yìí kọ́ ni ó ti máa ń jókòó, tí ó máa ń ṣagbe rí?” Àwọn kan ń sọ pé, “Òun ni!” Àwọn mìíràn ń sọ pé, “Rárá o, ó jọ ọ́ ni.” Ọkunrin náà ni, “Èmi gan-an ni.” Wọ́n bi í pé, “Báwo ni ojú rẹ́ ti ṣe là?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Ọkunrin tí wọn ń pè ní Jesu ni ó po amọ̀, tí ó fi lẹ̀ mí lójú, tí ó sọ fún mi pé kí n lọ bọ́jú ní adágún Siloamu. Mo lọ, mo bọ́jú, mo sì ríran.” Wọ́n bi í pé, “Níbo ni ọkunrin náà wà?” Ó dáhùn pé, “Èmi kò mọ̀.” Àwọn kan bá mú ọkunrin tí ojú rẹ̀ ti fọ́ rí yìí lọ sọ́dọ̀ àwọn Farisi. (Ọjọ́ Ìsinmi ni ọjọ́ tí Jesu po amọ̀, tí ó fi la ojú ọkunrin náà.) Àwọn Farisi tún bi ọkunrin náà bí ó ti ṣe ríran. Ó sọ fún wọn pé, “Ó lẹ amọ̀ mọ́ mi lójú, mo lọ bọ́jú, mo bá ríran.” Àwọn kan ninu àwọn Farisi ń sọ pé, “Ọkunrin yìí kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá, nítorí kò pa òfin Ọjọ́ Ìsinmi mọ́.” Ṣugbọn àwọn mìíràn ń sọ pé “Báwo ni ẹni tí ó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣe lè ṣe irú iṣẹ́ ìyanu yìí?” Ìyapa bá bẹ́ sáàrin wọn. Wọ́n tún bi ọkunrin afọ́jú náà pé, “Kí ni ìwọ alára sọ nípa lílà tí ó là ọ́ lójú?” Ọkunrin náà ní, “Wolii ni.” Àwọn Juu kò gbàgbọ́ pé ó ti fọ́jú rí kí ó tó ríran títí wọ́n fi pe àwọn òbí ọkunrin náà. Wọ́n bi wọ́n pé, “Ọmọ yín nìyí, tí ẹ sọ pé ẹ bí ní afọ́jú? Báwo ni ó ti ṣe wá ríran nisinsinyii?” Àwọn òbí rẹ̀ dáhùn pé, “A mọ̀ pé ọmọ wa nìyí; ati pé afọ́jú ni a bí i. Ṣugbọn àwa kò mọ̀ bí ó ti ṣe wá ń ríran nisinsinyii. Ẹ bi í, kì í ṣe ọmọde, yóo fi ẹnu ara rẹ̀ sọ bí ó ti rí.” Àwọn òbí rẹ̀ fèsì báyìí nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn Juu; nítorí àwọn Juu ti pinnu láti yọ ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ pé Jesu ni Mesaya kúrò ninu àwùjọ. Nítorí èyí ni àwọn òbí ọkunrin náà ṣe sọ pé, “Kì í ṣe ọmọde, ẹ bi òun alára léèrè.” Wọ́n tún pe ọkunrin náà tí ó ti fọ́jú rí lẹẹkeji, wọ́n wí fún un pé, “Sọ ti Ọlọrun! Ní tiwa, àwa mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọkunrin yìí.” Ọkunrin náà sọ fún wọn pé, “Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni o, tabi ẹlẹ́ṣẹ̀ kọ́, èmi kò mọ̀. Nǹkankan ni èmi mọ̀: afọ́jú ni mí tẹ́lẹ̀, ṣugbọn nisinsinyii, mo ríran.” Wọ́n bi í pé, “Kí ni ó ṣe sí ọ? Báwo ni ó ti ṣe là ọ́ lójú?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Mo ti sọ fun yín lẹ́ẹ̀kan ná, ṣugbọn ẹ kò fẹ́ gbọ́. Kí ló dé tí ẹ fi tún fẹ́ gbọ́? Àbí ẹ̀yin náà fẹ́ di ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ni?” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bú u, wọ́n ní, “Ìwọ ni ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ní tiwa, ọmọ-ẹ̀yìn Mose ni wá. Àwa mọ̀ pé Ọlọrun ti bá Mose sọ̀rọ̀, ṣugbọn a kò mọ ibi tí eléyìí ti yọ wá.” Ọkunrin náà dá wọn lóhùn pé, “Ohun ìyanu ni èyí! Ẹ kò mọ ibi tí ó ti yọ wá, sibẹ ó là mí lójú. A mọ̀ pé Ọlọrun kì í fetí sí ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn a máa fetí sí ẹnikẹ́ni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé a kò rí i gbọ́ pé ẹnikẹ́ni la ojú ẹni tí wọ́n bí ní afọ́jú rí. Bí ọkunrin yìí kò bá wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun, kì bá tí lè ṣe ohunkohun.” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ìwọ yìí tí wọ́n bí ninu ẹ̀ṣẹ̀, tí wọ́n tọ́ dàgbà ninu ẹ̀ṣẹ̀, o wá ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́!” Wọ́n bá tì í jáde. Jesu gbọ́ pé wọ́n ti ti ọkunrin náà jáde kúrò ninu ilé ìpàdé. Nígbà tí ó rí i, ó bí i pé, “Ìwọ gba Ọmọ-Eniyan gbọ́ bí?” Ọkunrin náà dáhùn pé, “Alàgbà, ta ni ẹni náà, kí n lè gbà á gbọ́?” Jesu wí fún un pé, “Èmi tí ò ń wò yìí, tí mò ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí ni ẹni náà.” Ọkunrin náà dáhùn pé, “Mo gbàgbọ́, Oluwa!” Ó bá dọ̀bálẹ̀ fún un. Jesu bá ní, “Kí n lè ṣe ìdájọ́ ni mo ṣe wá sí ayé yìí, kí àwọn tí kò ríran lè ríran, kí àwọn tí ó ríran lè di afọ́jú.” Farisi wà láàrin àwọn eniyan tí ó wà pẹlu rẹ̀, tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí. Wọ́n bi í pé, “Àbí àwa náà fọ́jú?” Jesu wí fún wọn pé, “Bí ó bá jẹ́ pé ẹ fọ́jú, ẹ kò bá tí ní ẹ̀bi. Ṣugbọn nisinsinyii tí ẹ sọ pé, ‘Àwa ríran’ ẹ̀bi yín wà sibẹ.” “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹni tí kò bá gba ẹnu-ọ̀nà wọ àgbàlá ilé tí àwọn aguntan ń sùn sí, ṣugbọn tí ó bá fo ìgànná wọlé, olè ati ọlọ́ṣà ni. Ṣugbọn ẹni tí ó bá gba ẹnu ọ̀nà wọlé ni olùṣọ́-aguntan. Òun ni olùṣọ́nà ń ṣí ìlẹ̀kùn fún. Àwọn aguntan a máa gbọ́ ohùn rẹ̀, a sì máa pe àwọn aguntan rẹ̀ ní orúkọ, a máa kó wọn lọ jẹ. Nígbà tí gbogbo àwọn aguntan rẹ̀ bá jáde, a máa lọ níwájú wọn, àwọn aguntan a sì tẹ̀lé e nítorí wọ́n mọ ohùn rẹ̀. Aguntan kò jẹ́ tẹ̀lé àlejò, sísá ni wọ́n máa ń sá fún un, nítorí wọn kò mọ ohùn àlejò.” Òwe yìí ni Jesu fi bá wọn sọ̀rọ̀, ṣugbọn ohun tí ó ń bá wọn sọ kò yé wọn. Jesu tún sọ pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, èmi ni ìlẹ̀kùn àwọn aguntan. Olè ati ọlọ́ṣà ni gbogbo àwọn tí wọ́n ti wá ṣiwaju mi. Ṣugbọn àwọn aguntan kò gbọ́ ti wọn. Èmi ni ìlẹ̀kùn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọ̀dọ̀ mi wọlé yóo rí ìgbàlà, yóo máa wọlé, yóo máa jáde, yóo sì máa rí oúnjẹ jẹ. Olè kì í wá lásán, àfi kí ó wá jalè, kí ó wá pa eniyan, kí ó sì wá ba nǹkan jẹ́. Èmi wá kí eniyan lè ní ìyè, kí wọn lè ní i lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. “Èmi ni olùṣọ́-aguntan rere. Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-aguntan rere, mo ṣetán láti kú nítorí àwọn aguntan. Alágbàṣe tí kì í ṣe olùṣọ́-aguntan, tí kì í sìí ṣe olówó aguntan, bí ó bá rí ìkookò tí ń bọ̀, a fi àwọn aguntan sílẹ̀, a sálọ. Ìkookò a gbé ninu àwọn aguntan lọ, a sì tú wọn ká, nítorí alágbàṣe lásán ni, kò bìkítà fún àwọn aguntan. Èmi ni olùṣọ́-aguntan rere. Mo mọ àwọn tèmi, àwọn tèmi náà sì mọ̀ mí, gẹ́gẹ́ bí Baba ti mọ̀ mí, tí èmi náà sì mọ Baba. Mo ṣetán láti kú nítorí àwọn aguntan. Mo tún ní àwọn aguntan mìíràn tí kò sí ninu agbo yìí. Mo níláti dà wọ́n wá. Wọn yóo gbọ́ ohùn mi. Wọn yóo wá di agbo kan lábẹ́ olùṣọ́-aguntan kan. “Ìdí rẹ̀ nìyí tí Baba fi fẹ́ràn mi nítorí mo ṣetán láti kú, kí n lè tún wà láàyè. Ẹnikẹ́ni kò gba ẹ̀mí mi, ṣugbọn èmi fúnra mi ni mo yọ̀ǹda rẹ̀. Mo ní àṣẹ láti yọ̀ǹda rẹ̀, mo ní àṣẹ láti tún gbà á pada. Àṣẹ yìí ni mo rí gbà láti ọ̀dọ̀ Baba mi.” Ìyapa tún bẹ́ sáàrin àwọn Juu nítorí ọ̀rọ̀ yìí. Ọpọlọpọ ninu wọn sọ pé, “Ó ní ẹ̀mí èṣù, orí rẹ̀ ti dàrú. Kí ni ẹ̀ ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí?” Àwọn mìíràn ń sọ pé, “Èyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù. Ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù lè la ojú afọ́jú?” Ní àkókò òtútù-nini, ó tó àkókò Àjọ̀dún Ìyàsímímọ́ Tẹmpili tí wọn ń ṣe ní Jerusalẹmu, Jesu ń rìn kiri ní apá ọ̀dẹ̀dẹ̀ tí wọn ń pè ní Ọ̀dẹ̀dẹ̀ Solomoni ninu Tẹmpili. Àwọn Juu bá pagbo yí i ká, wọ́n sọ fún un pé, “Nígbà wo ni ìwọ yóo tó fi ọkàn wa balẹ̀? Bí ìwọ bá ni Mesaya, sọ fún wa pàtó.” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo sọ fun yín, ẹ kò gbàgbọ́. Iṣẹ́ tí mò ń ṣe ní orúkọ Baba mi ń jẹ́rìí mi, ṣugbọn ẹ kò gbàgbọ́, nítorí ẹ kò sí ninu àwọn aguntan mi. Àwọn aguntan mi a máa gbọ́ ohùn mi, mo mọ̀ wọ́n, wọn a sì máa tẹ̀lé mi. Mo fún wọn ní ìyè ainipẹkun, wọn kò lè kú mọ́ laelae, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò lè já wọn gbà mọ́ mi lọ́wọ́. Ohun tí Baba mi ti fún mi tóbi ju ohun gbogbo lọ. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè já a gbà mọ́ Baba mi lọ́wọ́. Ọ̀kan ni èmi ati Baba mi.” Àwọn Juu tún ṣa òkúta láti sọ lù ú. Jesu wá bi wọ́n pé, “Ọpọlọpọ iṣẹ́ rere ni mo ti fihàn yín láti ọ̀dọ̀ Baba. Nítorí èwo ni ẹ fi fẹ́ sọ mí ní òkúta ninu wọn?” Àwọn Juu dá a lóhùn pé, “Kì í ṣe nítorí iṣẹ́ rere ni a fi fẹ́ sọ ọ́ ní òkúta, nítorí ọ̀rọ̀ àfojúdi tí o sọ sí Ọlọrun ni; nítorí pé ìwọ tí ó jẹ́ eniyan sọ ara rẹ di Ọlọrun.” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo ṣebí àkọsílẹ̀ kan wà ninu Òfin yín pé, ‘Ọlọrun sọ pé ọlọrun ni yín.’ Ìwé Mímọ́ kò ṣe é parẹ́. Bí Ọlọrun bá pe àwọn tí ó sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún ní ọlọ́run, kí ló dé tí ẹ fi sọ pé mò ń sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun nítorí mo wí pé, ‘Ọmọ Ọlọrun ni mí,’ èmi tí Baba yà sọ́tọ̀, tí ó rán wá sí ayé? Bí n kò bá ṣe iṣẹ́ Baba mi, ẹ má ṣe gbà mí gbọ́. Ṣugbọn bí mo bá ń ṣe é, èmi kọ́ ni kí ẹ gbàgbọ́, àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe ni kí ẹ gbàgbọ́. Èyí yóo jẹ́ kí ẹ wòye, kí ẹ wá mọ̀ pé Baba wà ninu mi, ati pé èmi náà wà ninu Baba.” Nígbà náà ni wọ́n tún ń wá ọ̀nà láti mú un, ṣugbọn ó jáde kúrò ní àrọ́wọ́tó wọn. Ó tún pada lọ sí òdìkejì odò Jọdani níbi tí Johanu tí ń ṣe ìrìbọmi ní àkọ́kọ́, ó bá ń gbé ibẹ̀. Ọpọlọpọ eniyan lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń sọ pé, “Johanu kò ṣe iṣẹ́ ìyanu kankan, ṣugbọn gbogbo ohun tí ó sọ nípa ọkunrin yìí ni ó rí bẹ́ẹ̀.” Ọpọlọpọ eniyan bá gbà á gbọ́ níbẹ̀. Ọkunrin kan tí ń jẹ́ Lasaru ń ṣàìsàn. Ní Bẹtani ni ó ń gbé, ní ìlú kan náà pẹlu Maria ati Mata arabinrin rẹ̀. Maria yìí ni obinrin tí ó tú òróró olóòórùn dídùn sára Oluwa ní ọjọ́ kan, tí ó fi irun orí rẹ̀ nu ẹsẹ̀ Jesu. Lasaru tí ó ń ṣàìsàn jẹ́ arakunrin Maria yìí. Àwọn arabinrin mejeeji yìí ranṣẹ lọ sọ́dọ̀ Jesu pé, “Oluwa, ẹni tí o fẹ́ràn ń ṣàìsàn.” Nígbà tí Jesu gbọ́, ó ní, “Àìsàn yìí kì í ṣe ti ikú, fún ògo Ọlọrun ni, kí á lè ṣe Ọmọ Ọlọrun lógo nípa rẹ̀ ni.” Jesu fẹ́ràn Mata ati arabinrin rẹ̀ ati Lasaru. Nígbà tí Jesu gbọ́ pé Lasaru ń ṣàìsàn, kò kúrò ní ibi tí ó wà fún ọjọ́ meji. Lẹ́yìn náà ni ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí á tún pada lọ sí Judia.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Olùkọ́ni, láìpẹ́ yìí ni àwọn Juu ń fẹ́ sọ ọ́ ní òkúta, o tún fẹ́ lọ sibẹ?” Jesu ní, “Ṣebí wakati mejila ni ó wà ninu ọjọ́ kan? Bí ẹnikẹ́ni bá rìn ní ọ̀sán kò ní kọsẹ̀, nítorí ó ń fi ìmọ́lẹ̀ ayé yìí ríran. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá ń rìn lálẹ́ níí kọsẹ̀, nítorí kò sí ìmọ́lẹ̀ ninu rẹ̀.” Lẹ́yìn tí ó ti sọ báyìí tán, ó sọ fún wọn pé, “Lasaru ọ̀rẹ́ wa ti sùn, mò ń lọ jí i.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Oluwa, bí ó bá sùn, yóo tún jí.” Ohun tí Jesu ń sọ̀rọ̀ bá ni ikú Lasaru, ṣugbọn wọ́n rò pé nípa oorun sísùn ni ó ń sọ. Nígbà náà ni Jesu wá wí fún wọn pàtó pé, “Lasaru ti kú. Ó dùn mọ́ mi nítorí yín pé n kò sí níbẹ̀, kí ẹ lè gbàgbọ́. Ẹ jẹ́ kí á lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.” Nígbà náà ni Tomasi tí wọn ń pè ní Didimu (tí ìtumọ̀ rẹ̀ jẹ́ “Ìbejì”) sọ fún àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ kí àwa náà lè bá a kú.” Nígbà tí Jesu dé, ó rí i pé ó ti tó ọjọ́ mẹrin tí òkú náà ti wà ninu ibojì. Bẹtani kò jìnnà sí Jerusalẹmu, kò ju ibùsọ̀ meji lọ. Ọpọlọpọ ninu àwọn Juu ni wọ́n wá láti Jerusalẹmu sọ́dọ̀ Mata ati Maria láti tù wọ́n ninu nítorí ikú arakunrin wọn. Nígbà tí Mata gbọ́ pé Jesu ń bọ̀, ó jáde lọ pàdé rẹ̀. Ṣugbọn Maria jókòó ninu ilé. Mata sọ fún Jesu pé, “Oluwa, ìbá jẹ́ pé o wà níhìn-ín, arakunrin mi kì bá tí kú! Ṣugbọn nisinsinyii náà, mo mọ̀ pé ohunkohun tí o bá bèèrè lọ́wọ́ Ọlọrun, yóo ṣe é fún ọ.” Jesu wí fún un pé, “Arakunrin rẹ yóo jí dìde.” Mata dá a lóhùn pé, “Mo mọ̀ pé yóo jí dìde ní ajinde ọjọ́ ìkẹyìn.” Jesu wí fún un pé, “Èmi ni ajinde ati ìyè. Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ kú, sibẹ yóo yè. Gbogbo ẹni tí ó bá wà láàyè, tí ó bá gbà mí gbọ́, kò ní kú laelae. Ǹjẹ́ o gba èyí gbọ́?” Ó dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa, mo gbàgbọ́ pé ìwọ ni Mesaya Ọmọ Ọlọrun tí ó ń bọ̀ wá sí ayé.” Nígbà tí Mata ti sọ báyìí tán, ó lọ pe Maria arabinrin rẹ̀ sí ìkọ̀kọ̀. Ó ní, “Olùkọ́ni ti dé, ó ń pè ọ́.” Bí Maria ti gbọ́, ó dìde kíá, ó bá lọ sọ́dọ̀ Jesu. (Jesu kò tíì wọ ìlú, ó wà ní ibi tí Mata ti pàdé rẹ̀.) Nígbà tí àwọn Juu tí ó wà ninu ilé pẹlu Maria, tí wọn ń tù ú ninu, rí i pé ó sáré dìde, ó jáde, àwọn náà tẹ̀lé e, wọ́n ṣebí ó ń lọ sí ibojì láti lọ sunkún ni. Nígbà tí Maria dé ibi tí Jesu wà, bí ó ti rí i, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Oluwa, ìbá jẹ́ pé o wà níhìn-ín, arakunrin mi kì bá tí kú.” Nígbà tí Jesu rí i tí ó ń sunkún, tí àwọn Juu tí ó bá a jáde tún ń sunkún, orí rẹ̀ wú, ọkàn rẹ̀ wá bàjẹ́. Ó bi wọ́n pé, “Níbo ni ẹ tẹ́ ẹ sí?” Wọ́n sọ fún un pé, “Oluwa, wá wò ó.” Ni Jesu bá bú sẹ́kún. Nígbà náà ni àwọn Juu sọ pé, “Ẹ ò rí i bí ó ti fẹ́ràn rẹ̀ tó!” Àwọn kan ninu wọn ń sọ pé, “Ọkunrin yìí tí ó la ojú afọ́jú, ǹjẹ́ kò lè ṣe é kí ọkunrin yìí má fi kú?” Orí Jesu tún wú, ó bá lọ síbi ibojì. Ninu ihò òkúta ni ibojì náà wà, òkúta sì wà ní ẹnu ọ̀nà rẹ̀. Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ gbé òkúta náà kúrò.” Mata, arabinrin ẹni tí ó kú, sọ fún un pé, “Oluwa, ó ti ń rùn, nítorí ó ti di òkú ọjọ́ mẹrin!” Jesu wí fún un pé, “Ṣebí mo ti sọ fún ọ pé bí o bá gbàgbọ́ ìwọ yóo rí ògo Ọlọrun.” Wọ́n bá gbé òkúta náà kúrò. Jesu gbé ojú sókè, ó ní, “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ nítorí ò ń gbọ́ tèmi. Mo mọ̀ pé nígbà gbogbo ni ò ń gbọ́ tèmi, ṣugbọn nítorí ti àwọn eniyan tí ó dúró yíká ni mo ṣe sọ èyí kí wọ́n lè gbàgbọ́ pé ìwọ ni o rán mi níṣẹ́.” Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, ó kígbe sókè pé, “Lasaru, jáde wá!” Ẹni tí ó ti kú náà bá jáde pẹlu aṣọ òkú tí wọ́n fi wé e lọ́wọ́ ati lẹ́sẹ̀ ati ọ̀já tí wọ́n fi dì í lójú. Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ tú aṣọ kúrò lára rẹ̀, kí ẹ jẹ́ kí ó máa lọ.” Ọpọlọpọ ninu àwọn Juu tí ó wá sọ́dọ̀ Maria gba Jesu gbọ́ nígbà tí wọ́n rí ohun tí ó ṣe. Ṣugbọn àwọn kan ninu wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn Farisi, wọ́n lọ sọ ohun gbogbo tí Jesu ṣe. Àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi bá pe ìgbìmọ̀, wọ́n ní, “Kí ni a óo ṣe o, nítorí ọkunrin yìí ń ṣe iṣẹ́ ìyanu pupọ? Bí a bá fi í sílẹ̀ báyìí, gbogbo eniyan ni yóo gbà á gbọ́, àwọn ará Romu yóo bá wá, wọn yóo wo Tẹmpili yìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóo pa orílẹ̀-èdè wa run.” Nígbà náà ni ọ̀kan ninu wọn, Kayafa, tí ó jẹ́ Olórí Alufaa ní ọdún náà, sọ fún wọn pé, “Ẹ kò mọ nǹkankan! Ẹ kò rí i pé ó sàn kí ẹnìkan kú fún àwọn eniyan jù pé kí gbogbo orílẹ̀-èdè ṣègbé!” Kì í ṣe àròsọ ti ara rẹ̀ ni ó fi sọ gbolohun yìí, ṣugbọn nítorí ó jẹ́ olórí alufaa ní ọdún náà, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ ni, pé Jesu yóo kú fún orílẹ̀-èdè wọn. Kì í wá ṣe fún orílẹ̀-èdè wọn nìkan, ṣugbọn kí àwọn ọmọ Ọlọrun tí ó fọ́nká lè papọ̀ di ọ̀kan. Láti ọjọ́ náà ni wọ́n ti ń gbèrò ọ̀nà tí wọn yóo fi pa Jesu. Nítorí náà, Jesu kò rìn ní gbangba mọ́ láàrin àwọn Juu, ṣugbọn ó kúrò níbẹ̀, ó lọ sí ìlú kan lẹ́bàá aṣálẹ̀, tí ó ń jẹ́ Efuraimu. Níbẹ̀ ni ó ń gbé pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Nígbà tí ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá ti àwọn Juu, ọ̀pọ̀ eniyan gòkè lọ sí Jerusalẹmu láti ìgbèríko, kí ó tó tó àkókò àjọ̀dún, kí wọ́n lè ṣe ìwẹ̀mọ́ fún àjọ̀dún náà. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá Jesu, wọ́n ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ bí wọ́n ti dúró ninu Tẹmpili pé, “Kí ni ẹ rò? Ǹjẹ́ ó jẹ́ wá sí àjọ̀dún yìí?” Àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi ti pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ ibi tí Jesu wà, kí ó wá sọ, kí wọ́n lè mú un. Nígbà tí Àjọ̀dún Ìrékọjá ku ọjọ́ mẹfa, Jesu lọ sí Bẹtani níbi tí Lasaru wà, ẹni tí ó kú, tí Jesu jí dìde. Wọ́n se àsè kan fún un níbẹ̀. Mata ń ṣe ètò gbígbé oúnjẹ kalẹ̀; Lasaru wà ninu àwọn tí ó ń bá Jesu jẹun. Nígbà náà ni Maria dé, ó mú ìgò kékeré kan lọ́wọ́. Ojúlówó òróró ìpara kan, olówó iyebíye ni ó wà ninu ìgò náà. Ó bá tú òróró yìí sí Jesu lẹ́sẹ̀, ó ń fi irun orí rẹ̀ nù ún. Òórùn òróró náà bá gba gbogbo ilé. Judasi Iskariotu, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ẹni tí yóo fi í lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, sọ pé, “Kí ló dé tí a kò ta òróró yìí ní nǹkan bí ọọdunrun (300) owó fadaka, kí á pín in fún àwọn talaka?” Kì í ṣe nítorí pé ó bìkítà fún àwọn talaka ni ó ṣe sọ bẹ́ẹ̀; nítorí pé ó jẹ́ olè ni. Òun ni akápò; a máa jí ninu owó tí wọn bá fi pamọ́. Jesu dá a lóhùn pé, “Fi í sílẹ̀! Jẹ́ kí ó fi pamọ́ di ọjọ́ ìsìnkú mi. Nígbà gbogbo ni àwọn talaka wà lọ́dọ̀ yín, ṣugbọn èmi kò ní sí lọ́dọ̀ yín nígbà gbogbo.” Nígbà tí ọpọlọpọ ninu àwọn Juu mọ̀ pé Jesu wà ní Bẹtani, wọ́n lọ sibẹ, kì í ṣe nítorí ti Jesu nìkan, ṣugbọn nítorí kí wọ́n lè rí Lasaru tí Jesu jí dìde kúrò ninu òkú. Àwọn olórí alufaa bá pinnu láti pa Lasaru, nítorí pé nítorí rẹ̀ ni ọpọlọpọ àwọn Juu ṣe ń kúrò ninu ẹ̀sìn wọn, tí wọn ń gba Jesu gbọ́. Ní ọjọ́ keji, ọpọlọpọ eniyan tí ó wá ṣe àjọ̀dún gbọ́ pé Jesu ń bọ̀ wá sí Jerusalẹmu. Wọ́n bá mú imọ̀ ọ̀pẹ, wọ́n jáde lọ pàdé rẹ̀, wọ́n ń kígbe pé, “Hosana! Olùbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ ní orúkọ Oluwa ati ọba Israẹli.” Jesu rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan, ó bá gùn un, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Má bẹ̀rù mọ́, ọdọmọbinrin Sioni, Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá, ó gun ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.” Gbogbo nǹkan wọnyi kò yé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní àkókò yìí, ṣugbọn nígbà tí a ti ṣe Jesu lógo, wọ́n ranti pé a ti kọ gbogbo nǹkan wọnyi nípa rẹ̀ ati pé wọ́n ti ṣe gbogbo nǹkan wọnyi sí i. Àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu Jesu nígbà tí ó fi pe Lasaru jáde kúrò ninu ibojì, tí ó jí i dìde kúrò ninu òkú, ń ròyìn ohun tí wọ́n rí. Nítorí èyí ni àwọn eniyan ṣe lọ pàdé rẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ó ṣe iṣẹ́ ìyanu yìí. Àwọn Farisi bá ń bá ara wọn sọ pé, “Ẹ jókòó lásán ni! Òfo ni gbogbo làálàá yín já sí! Ẹ kò rí i pé gbogbo eniyan ni wọ́n ti tẹ̀lé e tán!” Àwọn Giriki mélòó kan wà ninu àwọn tí ó gòkè lọ sí Jerusalẹmu láti jọ́sìn ní àkókò àjọ̀dún náà. Wọ́n lọ sọ́dọ̀ Filipi tí ó jẹ́ ará Bẹtisaida, ìlú kan ní Galili, wọ́n sọ fún un pé, “Alàgbà, a fẹ́ rí Jesu.” Filipi lọ sọ fún Anderu, Anderu ati Filipi bá jọ lọ sọ fún Jesu. Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àkókò náà dé wàyí tí a óo ṣe Ọmọ-Eniyan lógo. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé bí ẹyọ irúgbìn kan kò bá bọ́ sílẹ̀, kí ó kú, òun nìkan ni yóo dá wà. Ṣugbọn bí ó bá kú, á mú ọpọlọpọ èso wá. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn ẹ̀mí rẹ̀ yóo pàdánù rẹ̀, ṣugbọn ẹni tí ó bá kórìíra ẹ̀mí rẹ̀ ní ayé yìí yóo pa á mọ́ títí di ìyè ainipẹkun. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ jẹ́ iranṣẹ mi, ó níláti tẹ̀lé mi. Níbi tí èmi alára bá wà, níbẹ̀ ni iranṣẹ mi yóo wà. Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ iranṣẹ mi, Baba mi yóo dá a lọ́lá.” Jesu bá tún sọ pé, “Ọkàn mí dàrú nisinsinyii. Kí ni ǹ bá wí? Ọkàn kan ń sọ pé kí n wí pé, ‘Baba, yọ mí kúrò ninu àkókò yìí.’ Ṣugbọn nítorí àkókò yìí gan-an ni mo ṣe wá sí ayé. Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo.” Ohùn kan bá wá láti ọ̀run, ó ní, “Mo ti ṣe é lógo ná, èmi óo sì tún ṣe é lógo sí i.” Ọpọlọpọ ninu àwọn eniyan tí wọ́n dúró, tí wọ́n gbọ́, ń sọ pé, “Ààrá sán!” Àwọn ẹlòmíràn ń sọ pé, “Angẹli ló bá a sọ̀rọ̀.” Jesu wí fún wọn pé, “Ohùn yìí kò wá nítorí tèmi bí kò ṣe nítorí tiyín. Àkókò tó fún ìdájọ́ ayé yìí. Nisinsinyii ni a óo lé aláṣẹ ayé yìí jáde. Ní tèmi, bí a bá gbé mi sókè kúrò láyé, n óo fa gbogbo eniyan sọ́dọ̀ mi.” Ó sọ èyí, ó fi ṣe àkàwé irú ikú tí yóo kú. Àwọn eniyan bi í pé, “A gbọ́ ninu òfin pé Mesaya wà títí lae. Kí ni ìtumọ̀ ohun tí o sọ pé dandan ni kí á gbé Ọmọ-Eniyan sókè? Ta ni ń jẹ́ Ọmọ-Eniyan?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ìmọ́lẹ̀ wà láàrin yín fún àkókò díẹ̀ sí i. Ẹ máa rìn níwọ̀n ìgbà tí ẹ ní ìmọ́lẹ̀, kí òkùnkùn má baà bò yín mọ́lẹ̀. Ẹni tí ó bá ń rìn ninu òkùnkùn kò mọ ibi tí ó ń lọ. Níwọ̀n ìgbà tí ẹ ní ìmọ́lẹ̀, ẹ gba ìmọ́lẹ̀ náà gbọ́, kí ẹ lè jẹ́ ọmọ ìmọ́lẹ̀.” Nígbà tí Jesu sọ báyìí tán, ó fara pamọ́ fún wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jesu ti ṣe ọpọlọpọ iṣẹ́ ìyanu lójú wọn, sibẹ wọn kò gbà á gbọ́. Èyí mú kí ọ̀rọ̀ wolii Aisaya ṣẹ nígbà tí ó sọ pé, “Oluwa, ta ni ó gba ìròyìn wa gbọ́? Ta ni a fi agbára Oluwa hàn fún?” Nítorí èyí ni wọn kò fi lè gbàgbọ́, nítorí Aisaya tún sọ pé, “Ojú wọn ti fọ́, ọkàn wọn sì ti le; kí wọn má baà fi ojú wọn ríran, kí òye má baà yé wọn. Kí wọn má baà yipada, kí n má baà wò wọ́n sàn.” Aisaya sọ nǹkan wọnyi nítorí ó rí ògo Jesu, ó wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀. Sibẹ ọpọlọpọ ninu àwọn aṣaaju gbà á gbọ́; ṣugbọn wọn kò jẹ́wọ́ nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn Farisi, kí wọn má baà yọ wọ́n kúrò ninu àwùjọ; nítorí wọ́n fẹ́ràn ìyìn eniyan ju ìyìn Ọlọrun lọ. Jesu bá kígbe pé, “Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, kì í ṣe èmi ni ó gbàgbọ́ bíkòṣe ẹni tí ó rán mi níṣẹ́. Ẹni tí ó bá rí mi, ó rí ẹni tí ó rán mi. Mo wá sinu ayé bí ìmọ́lẹ̀, kí ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́ má baà wà ninu òkùnkùn. Bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí kò bá pa á mọ́, èmi kò ní dá a lẹ́jọ́, nítorí n kò wá sí ayé láti ṣe ìdájọ́, ṣugbọn mo wá láti gba aráyé là. Ẹni tí ó bá kọ̀ mí, tí kò gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́, ó ní ohun tí yóo dá a lẹ́jọ́, ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ ni yóo dá a lẹ́jọ́ ní ọjọ́ ìkẹyìn. Nítorí kì í ṣe ọ̀rọ̀ ti ara mi ni mò ń sọ, bíkòṣe ti Baba tí ó rán mi níṣẹ́, tí ó ti fún mi ní àṣẹ ohun tí n óo sọ ati ohun tí n óo wí. Mo mọ̀ pé òfin rẹ̀ ń tọ́ni sí ìyè ainipẹkun. Nítorí náà, bí Baba ti sọ fún mi pé kí n wí, bẹ́ẹ̀ gan-an ni mò ń sọ.” Nígbà tí àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá ku ọjọ́ kan, Jesu mọ̀ pé àkókò tó, tí òun yóo kúrò láyé yìí lọ sọ́dọ̀ Baba. Fífẹ́ tí ó fẹ́ràn àwọn eniyan rẹ̀ tó wà láyé yìí, ó fẹ́ràn wọn dé òpin. Bí wọ́n ti ń jẹun, Èṣù ti fi sí Judasi ọmọ Simoni Iskariotu lọ́kàn láti fi Jesu lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́. Jesu mọ̀ pé Baba ti fi ohun gbogbo lé òun lọ́wọ́, ati pé ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni òun ti wá, ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni òun sì ń lọ. Ó bá dìde nídìí oúnjẹ, ó bọ́ agbádá rẹ̀ sílẹ̀, ó mú aṣọ ìnura, ó lọ́ ọ mọ́ ìbàdí, ó bu omi sinu àwokòtò kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí fọ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ń fi aṣọ ìnura tí ó lọ́ mọ́ ìbàdí nù wọ́n lẹ́sẹ̀. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Simoni Peteru, Peteru bi í pé, “Oluwa, ìwọ ni o fẹ́ fọ ẹsẹ̀ mi?” Jesu dá a lóhùn pé, “O kò mọ ohun tí mò ń ṣe nisinsinyii; ṣugbọn yóo yé ọ tí ó bá yá.” Peteru dá a lóhùn pé, “O kò ní fọ ẹsẹ̀ mi laelae!” Jesu wí fún un pé, “Bí n kò bá wẹ̀ ọ́, a jẹ́ pé ìwọ kò ní nǹkankan ṣe pẹlu mi.” Simoni Peteru bá sọ fún un pé, “Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, Oluwa, ẹsẹ̀ mi nìkan kọ́, ati ọwọ́ ati orí mi ni kí o fọ̀ pẹlu.” Jesu wí fún un pé, “Ẹni tí ó bá ti wẹ̀ nílé, tí ó bá jáde, kò sí ohun tí ó kù jù pé kí á fọ ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ, gbogbo ara rẹ̀ á wá di mímọ́. Ẹ̀yin mọ́, ṣugbọn kì í ṣe gbogbo yín.” Ó ti mọ ẹni tí yóo fi òun lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́; nítorí náà ni ó ṣe sọ pé, “Kì í ṣe gbogbo yín ni ó mọ́.” Nígbà tí ó ti fọ ẹsẹ̀ wọn tán, ó wọ agbádá rẹ̀, ó bá tún jókòó. Ó wá bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí mo ṣe si yín? Ẹ̀ ń pè mí ní Olùkọ́ni ati Oluwa. Ó dára, nítorí bẹ́ẹ̀ ni mo jẹ́. Bí èmi Oluwa ati Olùkọ́ni yín bá fọ ẹsẹ̀ yín, ó yẹ kí ẹ máa fọ ẹsẹ̀ ẹnìkejì yín. Àpẹẹrẹ ni mo fi fun yín pé, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe si yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ máa ṣe. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé: ẹrú kò ju oluwa rẹ̀ lọ, iranṣẹ kò ju ẹni tí ó rán an níṣẹ́ lọ. Bí ẹ bá mọ nǹkan wọnyi, ẹ óo láyọ̀ bí ẹ bá ń ṣe wọ́n. “Gbogbo yín kọ́ ni ọ̀rọ̀ mi yìí kàn. Mo mọ àwọn tí mo yàn. Ṣugbọn Ìwé Mímọ́ níláti ṣẹ tí ó sọ pé, ‘Ẹni tí ó ń bá mi jẹun ni ó ń jìn mí lẹ́sẹ̀.’ Mo wí fun yín nisinsinyii kí ó tó ṣẹlẹ̀, kí ẹ lè mọ ẹni tí èmi í ṣe nígbà tí ó bá ti ṣẹlẹ̀ tán. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ẹni tí ó bá gba ẹnikẹ́ni tí mo rán níṣẹ́, èmi ni ó gbà. Ẹni tí ó bá gbà mí, ó gba ẹni tí ó rán mi níṣẹ́.” Nígbà tí Jesu sọ báyìí tán, ọkàn rẹ̀ dàrú. Ó bá wí tẹ̀dùntẹ̀dùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ọ̀kan ninu yín ni yóo fi mí lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí wo ara wọn lójú; nítorí ohun tí Jesu sọ rú wọn lójú. Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu, ẹni tí ó fẹ́ràn, jókòó níbi oúnjẹ, ó súnmọ́ Jesu pẹ́kípẹ́kí. Simoni Peteru bá ṣẹ́jú sí i pé kí ó bèèrè pé ta ni ọ̀rọ̀ náà ń bá wí. Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà túbọ̀ súnmọ́ Jesu sí i, ó bi í pé, “Oluwa, ta ni rí?” Jesu dáhùn pé, “Ẹni tí mo bá fún ní òkèlè lẹ́yìn tí mo bá ti fi run ọbẹ̀ tán ni ẹni náà.” Nígbà tí ó ti fi òkèlè run ọbẹ̀, ó mú un fún Judasi ọmọ Iskariotu. Lẹ́yìn tí Judasi ti gba òkèlè náà, Satani wọ inú rẹ̀. Jesu bá wí fún un pé, “Tètè ṣe ohun tí o níí ṣe.” Kò sí ẹnìkan ninu àwọn tí wọ́n jọ ń jẹun tí ó mọ ìdí tí Jesu fi sọ ọ̀rọ̀ yìí fún un. Nígbà tí ó jẹ́ pé Judasi ni akápò, àwọn mìíràn ń rò pé ohun tí Jesu sọ fún un ni pé, “Lọ ra àwọn ohun tí a óo lò fún Àjọ̀dún Ìrékọjá, tabi ohun tí a óo fún àwọn talaka.” Lẹsẹkẹsẹ tí Judasi ti gba òkèlè náà tán, ó jáde lọ. Ilẹ̀ ti ṣú nígbà náà. Nígbà tí Judasi jáde, Jesu wí pé, “Nisinsinyii ni ògo Ọmọ-Eniyan wá yọ. Ògo Ọlọrun pàápàá yọ lára Ọmọ-Eniyan. Bí ògo Ọlọrun bá wá yọ lára rẹ̀, Ọlọrun fúnrarẹ̀ yóo mú kí ògo Ọmọ-Eniyan yọ; lọ́gán ni yóo mú kí ògo rẹ̀ yọ. Ẹ̀yin ọmọ, àkókò díẹ̀ ni mo ní sí i pẹlu yín. Ẹ óo wá mi, ṣugbọn bí mo ti sọ fún àwọn Juu pé, ‘Níbi tí mò ń lọ, ẹ̀yin kò ní lè dé ibẹ̀,’ bẹ́ẹ̀ ni mo sọ fun yín nisinsinyii. Òfin titun ni mo fi fun yín, pé kí ẹ fẹ́ràn ara yín; gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹ́ràn yín ni kí ẹ fẹ́ràn ara yín. Èyí ni yóo jẹ́ kí gbogbo eniyan mọ̀ pé ọmọ-ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá fẹ́ràn ara yín.” Simoni Peteru bi í pé, “Oluwa, níbo ni ò ń lọ?” Jesu dá a lóhùn pé, “Níbi tí mò ń lọ, ìwọ kò lè tẹ̀lé mi nisinsinyii, ṣugbọn nígbà tí ó bá yá, ìwọ óo tẹ̀lé mi.” Peteru bi í pé, “Oluwa, kí ló dé tí n kò lè tẹ̀lé ọ nisinsinyii? Mo ṣetán láti kú nítorí rẹ.” Jesu dá a lóhùn pé, “O ṣetán láti kú nítorí mi? Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, kí àkùkọ tó kọ ìwọ óo sẹ́ mi lẹẹmẹta. “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín dàrú. Ẹ gba Ọlọrun gbọ́, kí ẹ sì gba èmi náà gbọ́. Yàrá pupọ ni ó wà ninu ilé Baba mi. Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ n óo sọ fun yín pé mò ń lọ pèsè àyè sílẹ̀ dè yín? Bí mo bá lọ pèsè àyè sílẹ̀ dè yín, n óo tún pada wá láti mu yín lọ sọ́dọ̀ ara mi, kí ẹ lè wà níbi tí èmi pàápàá bá wà. Ẹ kúkú ti mọ ọ̀nà ibi tí mò ń lọ.” Tomasi wí fún un pé, “Oluwa, a kò mọ ibi tí ò ń lọ, báwo ni a ti ṣe lè mọ ọ̀nà ibẹ̀?” Jesu wí fún un pé, “Èmi ni ọ̀nà, ati òtítọ́ ati ìyè. Kò sí ẹni tí ó lè dé ọ̀dọ̀ Baba bíkòṣe nípasẹ̀ mi. Bí ẹ bá ti mọ̀ mí, ẹ óo mọ Baba mi. Láti àkókò yìí, ẹ ti mọ̀ ọ́n, ẹ sì ti rí i.” Filipi sọ fún un pé, “Oluwa, fi Baba hàn wá, èyí náà sì tó wa.” Jesu wí fún un pé, “Bí mo ti pẹ́ lọ́dọ̀ yín tó yìí, sibẹ ìwọ kò mọ̀ mí, Filipi? Ẹni tí ó bá ti rí mi ti rí Baba. Kí ló dé tí o fi tún ń sọ pé, ‘Fi Baba hàn wá?’ Àbí o kò gbàgbọ́ pé mo wà ninu Baba ati pé Baba wà ninu mi ni? Èmi fúnra mi kọ́ ni mò ń sọ ọ̀rọ̀ tí mò ń sọ fun yín. Baba tí ó ń gbé inú mi ni ó ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀. Ẹ gbà mí gbọ́ pé mo wà ninu Baba ati pé Baba wà ninu mi. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ gbà mí gbọ́ nítorí iṣẹ́ wọnyi. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́ yóo ṣe àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe; yóo tilẹ̀ ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó ju ìwọ̀nyí lọ, nítorí mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba. Èmi yóo ṣe ohunkohun tí ẹ bá bèèrè ní orúkọ mi, kí ògo Baba lè yọ lára Ọmọ. Ohunkohun tí ẹ bá bèèrè lọ́wọ́ mi ní orúkọ mi, èmi yóo ṣe é. “Bí ẹ bá fẹ́ràn mi, ẹ óo pa òfin mi mọ́. N óo bèèrè lọ́wọ́ Baba, yóo wá fun yín ní Alátìlẹ́yìn mìíràn tí yóo wà pẹlu yín títí lae. Òun ni Ẹ̀mí tí ń fi òtítọ́ Ọlọrun hàn. Ayé kò lè gbà á nítorí ayé kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ̀ ọ́n. Ṣugbọn ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, nítorí ó ń ba yín gbé, ó sì wà ninu yín. “Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ bí aláìlárá. Mò ń pada bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín. Láìpẹ́, ayé kò ní rí mi mọ́, ṣugbọn ẹ̀yin yóo rí mi. Nítorí èmi wà láàyè, ẹ̀yin náà yóo wà láàyè. Ní ọjọ́ náà, ẹ̀yin yóo mọ̀ pé èmi wà ninu Baba mi, ati pé ẹ̀yin wà ninu mi, èmi náà sì wà ninu yín. “Ẹni tí ó bá gba òfin mi, tí ó sì pa wọ́n mọ́, òun ni ó fẹ́ràn mi. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn mi, Baba mi yóo fẹ́ràn rẹ̀, èmi náà yóo fẹ́ràn rẹ̀, n óo sì fi ara mi hàn án.” Judasi keji, (kì í ṣe Judasi Iskariotu), bi í pé, “Oluwa, kí ló dé tí o ṣe wí pé o kò ní fi ara rẹ han aráyé, ṣugbọn àwa ni ìwọ óo fi ara hàn?” Jesu dá a lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ràn mi yóo tẹ̀lé ọ̀rọ̀ mi. Baba mi yóo fẹ́ràn rẹ̀, èmi ati Baba mi yóo wá sọ́dọ̀ rẹ̀, a óo fi ọ̀dọ̀ rẹ̀ ṣe ibùgbé. Ẹni tí kò bá fẹ́ràn mi kò ní tẹ̀lé ọ̀rọ̀ mi. Ọ̀rọ̀ tí ẹ ń gbọ́ kì í ṣe tèmi, ti Baba tí ó rán mi níṣẹ́ ni. “Mo ti sọ nǹkan wọnyi fun yín nígbà tí mo ṣì wà lọ́dọ̀ yín. Ṣugbọn Alátìlẹ́yìn náà, Ẹ̀mí Mímọ́ tí Baba yóo rán wá ní orúkọ mi, ni yóo kọ yín, tí yóo sì ran yín létí ohun gbogbo tí mo sọ fun yín. “Alaafia ni mo fi sílẹ̀ fun yín. Alaafia mi ni mo fun yín. Kì í ṣe bí ayé ti í fúnni ni mo fun yín. Ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín dàrú, ẹ má sì jẹ́ kí ẹ̀rù bà yín. Ẹ gbọ́ nígbà tí mo sọ fun yín pé, ‘Mò ń lọ, ṣugbọn n óo tún pada wá sọ́dọ̀ yín.’ Bí ẹ bá fẹ́ràn mi ni, yíyọ̀ ni ẹ̀ bá máa yọ̀ pé, mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba, nítorí Baba jù mí lọ. Mo wí fun yín nisinsinyii kí ó tó ṣẹlẹ̀, kí ẹ lè gbàgbọ́ nígbà tí ó bá ṣẹlẹ̀ tán. N kò tún ní ohun pupọ ba yín sọ mọ́, nítorí aláṣẹ ayé yìí ń bọ̀. Kò ní agbára kan lórí mi. Ṣugbọn kí ayé lè mọ̀ pé mo fẹ́ràn Baba ni mo ṣe ń ṣe bí Baba ti pàṣẹ fún mi. “Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí á kúrò níhìn-ín. “Èmi ni àjàrà tòótọ́. Baba mi ni àgbẹ̀ tí ń mójútó ọgbà àjàrà. Gígé ni yóo gé gbogbo ẹ̀ka ara mi tí kò bá so èso, ṣugbọn yóo re ọwọ́ gbogbo ẹ̀ka tí ó bá ń so èso, kí wọ́n lè mọ́, kí wọ́n sì lè máa so sí i lọpọlọpọ. Ẹ̀yin ti di mímọ́ nítorí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fun yín. Ẹ máa gbé inú mi, èmi óo máa gbé inú yín. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka kò ti lè so èso fún ara rẹ̀ àfi bí ó bá wà lára igi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà kò lè so èso àfi bí ẹ bá ń gbé inú mi. “Èmi ni àjàrà, ẹ̀yin ni ẹ̀ka. Ẹni tí ó bá ń gbé inú mi, tí èmi náà sì ń gbé inú rẹ̀, yóo máa so èso pupọ. Ẹ kò lè dá ohunkohun ṣe lẹ́yìn mi. Bí ẹnikẹ́ni kò bá gbé inú mi, a óo jù ú sóde bí ẹ̀ka, yóo sì gbẹ; wọn óo mú un, wọn óo sì fi dáná, yóo bá jóná. Bí ẹ bá ń gbé inú mi, tí ọ̀rọ̀ mi ń gbé inú yín, ẹ óo bèèrè ohunkohun tí ẹ bá fẹ́, ẹ óo sì rí i gbà. Báyìí ni ògo Baba mi yóo ṣe yọ, pé kí ẹ máa so ọpọlọpọ èso. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi. Gẹ́gẹ́ bí Baba ti fẹ́ràn mi, bẹ́ẹ̀ ni mo fẹ́ràn yín. Ẹ máa gbé inú ìfẹ́ mi. Bí ẹ bá pa òfin mi mọ́, ẹ óo máa gbé inú ìfẹ́ mi, gẹ́gẹ́ bí mo ti pa òfin Baba mi mọ́, tí mo sì ń gbé inú ìfẹ́ rẹ̀. “Mo ti sọ nǹkan wọnyi fun yín kí ayọ̀ mi lè wà ninu yín, kí ẹ lè ní ayọ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Àṣẹ mi nìyí; ẹ fẹ́ràn ara yín gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹ́ràn yín. Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó ju èyí lọ, pé ẹnìkan kú nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ọ̀rẹ́ mi ni yín bí ẹ bá ń ṣe gbogbo nǹkan tí mo pa láṣẹ fun yín. N kò pè yín ní ọmọ-ọ̀dọ̀ mọ́, nítorí ọmọ-ọ̀dọ̀ kì í mọ ohun tí ọ̀gá rẹ̀ ń ṣe. Ṣugbọn mo pè yín ní ọ̀rẹ́, nítorí ohun gbogbo tí mo ti gbọ́ lọ́dọ̀ Baba mi ni mo ti fihàn yín. Kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ yàn mí. Èmi ni mo yàn yín, tí mo ran yín pé kí ẹ lọ máa so èso tí kò ní bàjẹ́, kí Baba lè fun yín ní ohunkohun tí ẹ bá bèèrè ní orúkọ mi. Àṣẹ yìí ni mo pa fun yín: ẹ fẹ́ràn ara yín. “Bí aráyé bá kórìíra yín, kí ẹ mọ̀ pé èmi ni wọ́n kọ́ kórìíra ṣáájú yín. Bí ó bá jẹ́ pé ti ayé ni yín, ayé ìbá fẹ́ràn yín bí àwọn ẹni tirẹ̀. Ṣugbọn ẹ kì í ṣe ti ayé nítorí mo ti yàn yín kúrò ninu ayé; ìdí rẹ̀ nìyí tí ayé fi kórìíra yín. Ẹ ranti ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fun yín, pé, ‘Ọmọ-ọ̀dọ̀ kò ju ọ̀gá rẹ̀ lọ.’ Bí wọ́n bá ṣe inúnibíni mi, wọn yóo ṣe inúnibíni yín. Bí wọ́n bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, wọn yóo pa ti ẹ̀yin náà mọ́. Wọn yóo ṣe gbogbo nǹkan wọnyi si yín nítorí tèmi, nítorí wọn kò mọ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́. Bí n kò bá wá láti bá wọn sọ̀rọ̀, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, wọn kò ní àwáwí fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ẹni tí ó bá kórìíra mi, kórìíra Baba mi. Bí n kò bá ṣe irú iṣẹ́ tí ẹnikẹ́ni kò ṣe rí, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, wọ́n ti rí àwọn iṣẹ́ mi, sibẹ wọ́n kórìíra èmi ati Baba mi. Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí a kọ ninu Òfin wọn lè ṣẹ pé, ‘Wọ́n kórìíra mi láìnídìí.’ “Nígbà tí Alátìlẹ́yìn tí n óo rán si yín láti ọ̀dọ̀ Baba bá dé, àní Ẹ̀mí tí ń fi òtítọ́ Ọlọrun hàn, tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Baba, yóo jẹ́rìí nípa mi. Ẹ̀yin náà yóo sì jẹ́rìí mi nítorí ẹ ti wà pẹlu mi láti ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ mi. “Mo sọ gbogbo nǹkan yìí fun yín kí igbagbọ yín má baà yẹ̀. Wọn yóo le yín jáde kúrò ninu ilé ìpàdé wọn. Èyí nìkan kọ́, àkókò ń bọ̀ tí ó jẹ́ pé ẹni tí ó bá ṣe ikú pa yín yóo rò pé òun ń ṣe iṣẹ́ ìsìn sí Ọlọrun ni. Wọn yóo ṣe nǹkan wọnyi nítorí wọn kò mọ Baba, wọn kò sì mọ̀ mí. Ṣugbọn mo ti sọ gbogbo nǹkan wọnyi fun yín, kí ẹ lè ranti pé mo ti sọ fun yín tẹ́lẹ̀, nígbà tí ó bá yá, tí wọn bá ń ṣe é si yín. “N kò sọ àwọn nǹkan wọnyi fun yín láti ìbẹ̀rẹ̀ nítorí mo wà lọ́dọ̀ yín. Ṣugbọn nisinsinyii mò ń lọ sọ́dọ̀ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́. Ẹnìkankan ninu yín kò wí pé, ‘Níbo ni ò ń lọ?’ Ṣugbọn ìbànújẹ́ kún ọkàn yín nítorí mo ti sọ nǹkan wọnyi fun yín. Sibẹ òtítọ́ ni mo sọ fun yín. Ó sàn fun yín pé kí n lọ. Nítorí bí n kò bá lọ, Alátìlẹ́yìn tí mo wí kò ní wá sọ́dọ̀ yín. Ṣugbọn bí mo bá lọ, n óo rán an si yín. Nígbà tí ó bá dé, yóo fi han aráyé pé wọ́n ti ṣìnà ninu èrò wọn nípa ẹ̀ṣẹ̀, ati nípa òdodo, ati nípa ìdájọ́ Ọlọrun. Wọ́n ti ṣìnà ninu èrò wọn nípa ẹ̀ṣẹ̀ nítorí pé wọn kò gbà mí gbọ́. Wọ́n ṣìnà ní ti òdodo nítorí mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba, ẹ kò sì ní rí mi mọ́. Wọ́n ṣìnà ní ti ìdájọ́ nítorí pé Ọlọrun ti dá aláṣẹ ayé yìí lẹ́bi. “Ọ̀rọ̀ tí mo tún fẹ́ ba yín sọ pọ̀, ṣugbọn ọkàn yin kò lè gbà á ní àkókò yìí. Ṣugbọn nígbà tí Ẹ̀mí òtítọ́ tí mo wí bá dé, yóo tọ yín sí ọ̀nà òtítọ́ gbogbo. Nítorí kò ní sọ ọ̀rọ̀ ti ara rẹ̀; gbogbo ohun tí ó bá gbọ́ ni yóo sọ. Yóo sọ àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ fun yín. Yóo fi ògo mi hàn nítorí láti ọ̀dọ̀ mi ni yóo ti gba àwọn ohun tí yóo sọ fun yín. Tèmi ni ohun gbogbo tí Baba ní. Ìdí nìyí ti mo ṣe sọ pé ohun tí ó bá gbà láti ọ̀dọ̀ mi ni yóo sọ fun yín. “Láìpẹ́ ẹ kò ní rí mi mọ́. Lẹ́yìn náà, láìpẹ́ ẹ óo sì tún rí mi.” Àwọn kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Kí ni ìtumọ̀ ohun tí ó wí fún wa yìí, ‘Láìpẹ́ ẹ kò ní rí mi mọ́. Lẹ́yìn náà, láìpẹ́ ẹ óo sì tún rí mi?’ Kí tún ni ìtumọ̀, ‘Nítorí mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba?’ ” Wọ́n tún ń sọ pé, “Kí ni ìtumọ̀ ‘Láìpẹ́’ tí ó ń wí yìí? Ohun tí ó ń sọ kò yé wa.” Jesu mọ̀ pé wọ́n ń fẹ́ bi òun léèrè ọ̀rọ̀ yìí. Ó wá wí fún wọn pé, “Nítorí èyí ni ẹ ṣe ń bá ara yín jiyàn, nítorí mo sọ pé, ‘Laìpẹ́ ẹ kò ní rí mi mọ́,’ ati pé, ‘Lẹ́yìn náà, láìpẹ́ ẹ óo tún rí mi?’ Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹ óo sunkún, ẹ óo ṣọ̀fọ̀, ṣugbọn inú aráyé yóo dùn. Ẹ óo dààmú ṣugbọn ìdààmú yín yóo di ayọ̀. Nígbà tí aboyún bá ń rọbí, ó gbọdọ̀ jẹ ìrora, nítorí àkókò ìkúnlẹ̀ rẹ̀ tó. Ṣugbọn nígbà tí ó bà bímọ tán, kò ní ranti gbogbo ìrora rẹ̀ mọ́, nítorí ayọ̀ pé ó bí ọmọ kan sinu ayé. Bákan náà ni: inú yín bàjẹ́ nisinsinyii, ṣugbọn n óo tún ri yín, inú yín yóo wá dùn, ẹnikẹ́ni kò ní lè mú ayọ̀ yín kúrò lọ́kàn yín. “Ní ọjọ́ náà, ẹ kò ní bi mí léèrè ohunkohun. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ohunkohun tí ẹ bá bèèrè lọ́dọ̀ Baba ní orúkọ mi, yóo fun yín. Ẹ kò ì tíì bèèrè ohunkohun ní orúkọ mi títí di ìsinsìnyìí. Ẹ bèèrè, ẹ óo sì rí gbà, kí ẹ lè ní ayọ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. “Bí òwe bí òwe ni mo ti ń sọ àwọn nǹkan yìí fun yín. Ṣugbọn àkókò ń bọ̀ nígbà tí n kò ní fi òwe ba yín sọ̀rọ̀ mọ́, kedere ni n óo máa sọ̀rọ̀ nípa Baba fun yín nígbà náà. Ní ọjọ́ náà, ẹ óo bèèrè nǹkan ní orúkọ mi, n kò ní wí fun yín pé èmi yóo ba yín bẹ Baba. Nítorí Baba fúnrarẹ̀ fẹ́ràn yín nítorí pé ẹ̀yin náà fẹ́ràn mi, ẹ ti gbàgbọ́ pé láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni mo ti wá. Mo wá láti ọ̀dọ̀ Baba, mo jáde wá sinu ayé, n óo tún fi ayé sílẹ̀ láti lọ sọ́dọ̀ Baba.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ pé, “Kedere ni ò ń sọ̀rọ̀ nisinsinyii, o kò sọ̀rọ̀ lówe lówe mọ́. A wá mọ̀ wàyí pé o mọ ohun gbogbo, kò ṣẹ̀ṣẹ̀ di ìgbà tí eniyan bá bi ọ́ kí o tó dáhùn ọ̀rọ̀. Nítorí náà, a gbàgbọ́ pé láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni o ti wá.” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ wá gbàgbọ́ nisinsinyii? Àkókò ń bọ̀, ó tilẹ̀ ti dé, nígbà tí ẹ óo túká, tí olukuluku yín yóo lọ sí ilé rẹ̀, tí ẹ óo fi èmi nìkan sílẹ̀. Ṣugbọn kò ní jẹ́ èmi nìkan nítorí Baba wà pẹlu mi. Mo ti sọ nǹkan wọnyi fun yín kí ẹ lè ní alaafia nípa wíwà ninu mi. Ẹ óo ní ìpọ́njú ninu ayé, ṣugbọn ẹ ṣe ara gírí, mo ti ṣẹgun ayé.” Lẹ́yìn tí Jesu ti sọ ọ̀rọ̀ wọnyi tán, ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó ní, “Baba, àkókò náà dé! Jẹ́ kí ògo rẹ hàn lára Ọmọ, kí ògo Ọmọ náà lè hàn lára rẹ. Gẹ́gẹ́ bí o ti fún un ní àṣẹ lórí ẹ̀dá gbogbo, pé kí ó lè fi ìyè ainipẹkun fún gbogbo ẹni tí o ti fún un. Ìyè ainipẹkun náà ni pé, kí wọ́n mọ̀ ọ́, ìwọ Ọlọrun tòótọ́ kanṣoṣo, kí wọ́n sì mọ Jesu Kristi ẹni tí o rán níṣẹ́. Èmi ti fi ògo fún ọ ninu ayé, mo ti parí iṣẹ́ tí o fún mi ṣe. Nisinsinyii, Baba, jẹ́ kí ògo rẹ hàn lára mi; àní kí irú ògo tí mo ti ní pẹlu rẹ kí a tó dá ayé tún hàn lára mi. “Mo ti fi orúkọ rẹ han àwọn eniyan tí o fún mi ninu ayé. Tìrẹ ni wọ́n, ìwọ ni o wá fi wọ́n fún mi. Wọ́n sì ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́. Nisinsinyii ó ti yé wọn pé láti ọ̀dọ̀ rẹ ni ohun gbogbo tí o fún mi ti wá. Nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí o fún mi ni mo ti fún wọn. Wọ́n ti gba àwọn ọ̀rọ̀ náà, ó ti wá yé wọn pé nítòótọ́, láti ọ̀dọ̀ rẹ ni mo ti wá, wọ́n sì gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi níṣẹ́. “Àwọn ni mò ń gbadura fún, n kò gbadura fún aráyé; ṣugbọn mò ń gbadura fún àwọn tí o ti fún mi, nítorí tìrẹ ni wọ́n. Ohun gbogbo tí mo ní, tìrẹ ni; ohun gbogbo tí ìwọ náà sì ní, tèmi ni. Wọ́n ti jẹ́ kí ògo mi yọ. Èmi kò ní sí ninu ayé mọ́, ṣugbọn àwọn wà ninu ayé. Èmi ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ. Baba mímọ́, fi agbára orúkọ rẹ pa àwọn tí o ti fi fún mi mọ́, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí àwa náà ti jẹ́ ọ̀kan. Nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ wọn, mo fi agbára orúkọ rẹ pa àwọn tí o ti fi fún mi mọ́. Mo pa wọ́n mọ́, ọ̀kan ninu wọn kò ṣègbé àfi ọmọ ègbé, kí Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ. Ṣugbọn nisinsinyii mò ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ. Mò ń sọ ọ̀rọ̀ wọnyi ninu ayé, kí wọ́n lè ní ayọ̀ mi lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ ninu ọkàn wọn. Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ fún wọn. Ayé kórìíra wọn nítorí wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi náà kì í ti ṣe tíí ayé. N kò bẹ̀bẹ̀ pé kí o mú wọn kúrò ninu ayé. Ẹ̀bẹ̀ mi ni pé kí o pa wọ́n mọ́ kúrò lọ́wọ́ Èṣù. Wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi kì í tíí ṣe ti ayé. Fi òtítọ́ yà wọ́n sí mímọ́ fún ara rẹ; òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ. Gẹ́gẹ́ bí o ti rán mi sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni mo rán wọn lọ sinu ayé. Nítorí tiwọn ni mo ṣe ya ara mi sí mímọ́, kí àwọn fúnra wọn lè di mímọ́ ninu òtítọ́. “N kò gbadura fún àwọn wọnyi nìkan. Ṣugbọn mo tún ń gbadura fún àwọn tí yóo gbà mí gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ wọn, pé kí gbogbo wọn lè jẹ́ ọ̀kan. Mo gbadura pé, gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Baba, ti wà ninu mi, tí èmi náà sì wà ninu rẹ, kí àwọn náà lè wà ninu wa, kí ayé lè gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi níṣẹ́. Ògo tí o fi fún mi ni mo fi fún wọn, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àwa náà ti jẹ́ ọ̀kan; èmi ninu wọn ati ìwọ ninu mi, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo, kí ayé lè mọ̀ pé ìwọ ni ó rán mi níṣẹ́, ati pé o fẹ́ràn wọn gẹ́gẹ́ bí o ti fẹ́ràn mi. “Baba, mo fẹ́ kí àwọn tí o fi fún mi wà pẹlu mi níbi tí èmi gan-an bá wà, kí wọ́n lè máa wo ògo tí o ti fi fún mi, nítorí o ti fẹ́ràn mi kí á tó fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀. Baba mímọ́, ayé kò mọ̀ ọ́, ṣugbọn èmi mọ̀ ọ́, ó ti yé àwọn wọnyi pé ìwọ ni ó rán mi níṣẹ́. Mo ti mú kí orúkọ rẹ hàn sí wọn, n óo sì tún fihàn, kí ìfẹ́ tí o fẹ́ mi lè wà ninu wọn, kí èmi náà sì wà ninu wọn.” Lẹ́yìn tí Jesu ti gba adura yìí tán, òun ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jáde lọ sí òdìkejì àfonífojì odò Kidironi. Ọgbà kan wà níbẹ̀. Ó wọ inú ọgbà náà, òun ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Judasi, ẹni tí ó fi í fún àwọn ọ̀tá, mọ ibẹ̀, nítorí ìgbà pupọ ni Jesu ti máa ń lọ sibẹ pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Judasi bá mú àwọn ọmọ-ogun ati àwọn ẹ̀ṣọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi, wọ́n wá sibẹ pẹlu ògùṣọ̀ ati àtùpà ati àwọn ohun ìjà. Nígbà tí Jesu rí ohun gbogbo tí yóo ṣẹlẹ̀ sí òun, ó jáde lọ pàdé wọn, ó bi wọ́n pé, “Ta ni ẹ̀ ń wá?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Jesu ará Nasarẹti ni.” Ó sọ fún wọn pé, “Èmi gan-an nìyí.” Judasi, ẹni tí ó fi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, dúró pẹlu wọn. Nígbà tí ó sọ fún wọn pé, “Èmi gan-an nìyí,” wọ́n bì sẹ́yìn, ni wọ́n bá ṣubú lulẹ̀. Ó tún bi wọ́n pé, “Ta ni ẹ̀ ń wá?” Wọ́n dáhùn pé, “Jesu ará Nasarẹti ni.” Jesu wí fún wọn pé, “Mo sọ fun yín pé èmi gan-an nìyí. Bí ó bá jẹ́ pé èmi ni ẹ̀ ń wá, ẹ jẹ́ kí àwọn wọnyi máa lọ.” (Kí ọ̀rọ̀ tí ó ti sọ lè ṣẹ tí ó wí pé, “Ọ̀kan kan kò ṣègbé ninu àwọn tí o ti fi fún mi.”) Nígbà náà ni Simoni Peteru tí ó ní idà kan fà á yọ, ó bá ṣá ẹrú Olórí Alufaa, ó gé e létí ọ̀tún. Maliku ni orúkọ ẹrú náà. Jesu bá sọ fún Peteru pé, “Ti idà rẹ bọ inú àkọ̀. Àbí kí n má jẹ ìrora ńlá tí Baba ti yàn fún mi ni?” Ni àwọn ọmọ-ogun ati ọ̀gágun ati àwọn ẹ̀ṣọ́ àwọn Juu bá mú Jesu, wọ́n dè é, wọ́n kọ́kọ́ fà á lọ sí ọ̀dọ̀ Anasi tíí ṣe baba iyawo Kayafa, tí ó jẹ́ Olórí Alufaa ní ọdún náà. Kayafa yìí ni ó fi ìmọ̀ràn fún àwọn Juu pé ó sàn kí ẹnìkan kú fún gbogbo eniyan. Ṣugbọn Simoni Peteru ń tẹ̀lé Jesu pẹlu ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn. Ọmọ-ẹ̀yìn keji yìí jẹ́ ẹni tí Olórí Alufaa mọ̀. Ṣugbọn Peteru dúró lóde lẹ́bàá ẹnu ọ̀nà. Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn keji tí Olórí Alufaa mọ̀ jáde, ó bá mú Peteru wọ agbo-ilé. Nígbà náà ni ọmọge tí ó ń ṣọ́nà sọ fún Peteru pé, “Ṣé kì í ṣe pé ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ọkunrin yìí ni ọ́?” Peteru dáhùn pé, “Rárá o!” Àwọn ẹrú ati àwọn ẹ̀ṣọ́ jọ dúró ní àgbàlá, wọ́n ń yáná tí wọ́n fi èédú dá, nítorí òtútù mú. Peteru náà dúró lọ́dọ̀ wọn, òun náà ń yáná. Olórí Alufaa bi Jesu nípa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ati nípa ẹ̀kọ́ rẹ̀. Jesu dá a lóhùn pé, “Ní gbangba ni èmi tí máa ń bá aráyé sọ̀rọ̀. Ninu ilé ìpàdé ati ninu Tẹmpili ni èmi tí máa ń kọ́ àwọn eniyan nígbà gbogbo, níbi tí gbogbo àwọn Juu ń péjọ sí, n kò sọ ohunkohun níkọ̀kọ̀. Kí ni ò ń bi mí sí? Bi àwọn tí ó ti gbọ́ ohun tí mo sọ fún wọn; wọ́n mọ ohun tí mo sọ.” Bí ó ti sọ báyìí tán ni ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀ṣọ́ tí ó dúró níbẹ̀ bá gbá Jesu létí, ó ní, “Olórí Alufaa ni o dá lóhùn bẹ́ẹ̀!” Jesu dá a lóhùn pé, “Bí burúkú ni mo bá sọ, wí ohun tí ó burú níbẹ̀ kí ayé gbọ́. Tí ó bá jẹ́ rere ni mo sọ, kí ló dé tí o fi lù mí?” Nígbà náà ni Anasi fi Jesu ranṣẹ ní dídè sí Kayafa, Olórí Alufaa. Simoni Peteru wà níbi tí ó dúró, tí ó ń yáná. Wọ́n sọ fún un pé, “Ṣé kì í ṣe pé ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ni ọ́?” Ó sẹ́, ó ní, “Rárá o!” Ọ̀kan ninu àwọn ẹrú Olórí Alufaa, tí ó jẹ́ ẹbí ẹni tí Peteru gé létí bi Peteru pé, “Ǹjẹ́ n kò rí ọ ninu ọgbà pẹlu rẹ̀?” Peteru tún sẹ́. Lẹsẹkẹsẹ àkùkọ kan bá kọ. Lẹ́yìn náà wọ́n mú Jesu kúrò níwájú Kayafa lọ sí ààfin. Ilẹ̀ ti mọ́ ní àkókò yìí. Àwọn fúnra wọn kò wọ inú ààfin, kí wọn má baà di aláìmọ́, kí wọn baà lè jẹ àsè Ìrékọjá. Pilatu bá jáde lọ sọ́dọ̀ wọn lóde, ó bi wọ́n pé, “Ẹ̀sùn wo ni ẹ fi kan ọkunrin yìí?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bí ọkunrin yìí kò bá ṣe nǹkan burúkú ni, a kì bá tí fà á lé ọ lọ́wọ́ fún ìdájọ́.” Pilatu sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin fúnra yín ẹ mú un lọ, kí ẹ ṣe ìdájọ́ fún un bí òfin yín.” Ṣugbọn àwọn Juu sọ fún un pé, “A kò ní àṣẹ láti ṣe ìdájọ́ ikú fún ẹnikẹ́ni.” Gbolohun yìí jáde kí ọ̀rọ̀ Jesu lè ṣẹ nígbà tí ó ń ṣàpẹẹrẹ irú ikú tí òun yóo kú. Pilatu bá tún wọ ààfin lọ, ó bi Jesu pé, “Ṣé ìwọ ni ọba àwọn Juu?” Jesu dáhùn pé, “O wí èyí fúnrarẹ ni àbí ẹlòmíràn ni ó sọ bẹ́ẹ̀ fún ọ nípa mi?” Pilatu dáhùn pé, “Èmi í ṣe Juu bí? Àwọn eniyan rẹ ati àwọn olórí alufaa ni wọ́n fà ọ́ wá sọ́dọ̀ mi. Kí ni o ṣe?” Jesu dá a lóhùn pé, “Ìjọba mi kì í ṣe ti ayé yìí. Bí ó bá jẹ́ pé ti ayé yìí ni ìjọba mi, àwọn iranṣẹ mi ìbá jà; àwọn Juu kì bá tí lè mú mi. Ṣùgbọ́n ìjọba mi kì í ṣe ti ìhín.” Pilatu wá bi í pé, “Èyí ni pé ọba ni ọ́?” Jesu dá a lóhùn pé, “O ti fi ẹnu ara rẹ wí pé Ọba ni mí. Nítorí rẹ̀ ni a ṣe bí mi, nítorí bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe wá sáyé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́. Gbogbo ẹni tí ó bá ń ṣe ti òtítọ́ yóo gbọ́ ohùn mi.” Pilatu bi í pé, “Kí ni òtítọ́?” Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, ó tún jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn Juu, ó sọ fún wọn pé, “Èmi kò rí ẹ̀bi kankan tí ó jẹ. Ṣugbọn ẹ ní àṣà kan, pé kí n dá ẹnìkan sílẹ̀ fun yín ní àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá. Ṣé ẹ fẹ́ kí n dá ‘Ọba àwọn Juu’ sílẹ̀ fun yín?” Wọ́n tún kígbe pé, “Òun kọ́! Baraba ni kí o dá sílẹ̀!” (Ọlọ́ṣà paraku ni Baraba yìí.) Nígbà náà ni Pilatu mú Jesu, ó ní kí wọ́n nà án. Àwọn ọmọ-ogun bá fi ìtàkùn ẹlẹ́gùn-ún hun adé, wọ́n fi dé e lórí; wọn wọ̀ ọ́ ní ẹ̀wù kan bíi ẹ̀wù àlàárì, wọ́n wá ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń kí i pé, “Kabiyesi! Ọba àwọn Juu!” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbá a létí. Pilatu tún jáde lọ sóde, ó sọ fún àwọn Juu pé, “Mò ń mú un tọ̀ yín bọ̀ wá sóde, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi kò rí i pé ó jẹ̀bi ohunkohun.” Nígbà náà ni Jesu jáde pẹlu adé ẹ̀gún ati ẹ̀wù àlàárì. Pilatu wá sọ fún wọn pé, “Ẹ wò ó, ọkunrin náà nìyí.” Nígbà tí àwọn olórí alufaa ati àwọn ẹ̀ṣọ́ rí i, wọ́n kígbe pé, “Kàn án mọ́ agbelebu!” Pilatu sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin fúnra yín ẹ mú un, kí ẹ kàn án mọ́ agbelebu, nítorí ní tèmi, n kò rí ẹ̀bi kankan tí ó jẹ.” Àwọn Juu dá a lóhùn pé, “A ní òfin kan, nípa òfin náà, ikú ni ó tọ́ sí i, nítorí ó fi ara rẹ̀ ṣe Ọmọ Ọlọrun.” Nígbà tí Pilatu gbọ́ gbolohun yìí, ẹ̀rù túbọ̀ bà á. Ó bá tún wọ ààfin lọ, ó bi Jesu pé, “Níbo ni o ti wá?” Ṣugbọn Jesu kò dá a lóhùn. Nígbà náà ni Pilatu sọ fún un pé, “Èmi ni ìwọ kò dá lóhùn? O kò mọ̀ pé mo ní àṣẹ láti dá ọ sílẹ̀, mo sì ní àṣẹ láti kàn ọ́ mọ́ agbelebu?” Jesu dá a lóhùn pé, “O kò ní àṣẹ lórí mi àfi èyí tí a ti fi fún ọ láti òkè wá. Nítorí náà, ẹni tí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ pọ̀jù ni ẹni tí ó fà mí lé ọ lọ́wọ́.” Láti ìgbà náà ni Pilatu ti ń wá ọ̀nà láti dá Jesu sílẹ̀. Ṣugbọn àwọn Juu ń kígbe pé, “Bí o bá dá ọkunrin yìí sílẹ̀, ìwọ kì í ṣe ọ̀rẹ́ Kesari, gbogbo ẹni tí ó bá fi ara rẹ̀ jọba lòdì sí Kesari.” Nígbà tí Pilatu gbọ́ bẹ́ẹ̀, ó mú Jesu jáde, ó wá jókòó lórí pèpéle ìdájọ́ níbìkan tí wọn ń pè ní “Pèpéle olókùúta,” tí ń jẹ́ “Gabata” ní èdè Heberu. Ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ fún Àjọ̀dún Ìrékọjá ni ọjọ́ náà. Ó tó nǹkan agogo mejila ọ̀sán. Pilatu sọ fún àwọn Juu pé, “Ọba yín nìyí!” Ṣugbọn àwọn Juu kígbe pé, “Mú un kúrò! Mú un kúrò! Kàn án mọ́ agbelebu!” Pilatu sọ fún wọn pé, “Kí n kan ọba yín mọ́ agbelebu?” Àwọn olórí alufaa dá a lóhùn pé, “A kò ní ọba lẹ́yìn Kesari.” Pilatu bá fa Jesu fún wọn láti kàn mọ́ agbelebu. Wọ́n bá gba Jesu lọ́wọ́ Pilatu. Ó ru agbelebu rẹ̀ jáde lọ sí ibìkan tí ó ń jẹ́ “Ibi Agbárí,” tí wọn ń pè ní “Gọlgọta” ní èdè Heberu. Níbẹ̀ ni wọ́n ti kàn án mọ́ agbelebu, òun ati àwọn meji kan, ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún, ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ òsì, Jesu wá wà láàrin. Pilatu kọ àkọlé kan, ó fi sórí agbelebu. Ohun tí ó kọ sórí rẹ̀ ni pé, “Jesu ará Nasarẹti, ọba àwọn Juu.” Pupọ ninu àwọn Juu ni ó ka àkọlé náà ní èdè Heberu ati ti Latini ati ti Giriki. Àwọn olórí alufaa àwọn Juu sọ fún Pilatu pé, “Má ṣe kọ ọ́ pé ‘Ọba àwọn Juu,’ ṣugbọn kọ ọ́ báyìí: ‘Ó ní: èmi ni ọba àwọn Juu.’ ” Ṣugbọn Pilatu dá wọn lóhùn pé, “Ohun tí mo ti kọ, mo ti kọ ọ́ ná.” Nígbà tí wọ́n kan Jesu mọ́ agbelebu tán, àwọn ọmọ-ogun pín àwọn aṣọ rẹ̀ sí ọ̀nà mẹrin, wọ́n mú un ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. Ó wá tún ku àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀. Àwọ̀tẹ́lẹ̀ yìí kò ní ojúùrán, híhun ni wọ́n hun ún láti òkè dé ilẹ̀. Wọ́n bá ara wọn sọ pé, “Ẹ má jẹ́ kí á ya á, gègé ni kí ẹ jẹ́ kí á ṣẹ́ láti mọ ti ẹni tí yóo jẹ́.” Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ tí ó wí pé, “Wọ́n pín aṣọ mi láàrin ara wọn, wọ́n ṣẹ́ gègé lórí ẹ̀wù mi.” Bẹ́ẹ̀ gan-an ni àwọn ọmọ-ogun sì ṣe. Ìyá Jesu ati arabinrin ìyá rẹ̀ ati Maria aya Kilopasi ati Maria Magidaleni dúró lẹ́bàá agbelebu Jesu. Nígbà tí Jesu rí ìyá rẹ̀ ati ọmọ-ẹ̀yìn tí ó fẹ́ràn tí wọ́n dúró, ó wí fún ìyá rẹ̀ pé, “Obinrin, wo ọmọ rẹ.” Ó bá sọ fún ọmọ-ẹ̀yìn náà pé, “Wo ìyá rẹ.” Láti ìgbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà ti mú ìyá Jesu lọ sílé ara rẹ̀. Lẹ́yìn èyí, nígbà tí Jesu mọ̀ pé ohun gbogbo ti parí, kí Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ, ó ní, “Òùngbẹ ń gbẹ mí.” Àwo ọtí kan wà níbẹ̀. Wọ́n bá fi kinní kan bíi kànìnkànìn bọ inú ọtí náà, wọ́n fi sórí ọ̀pá gígùn kan, wọ́n nà án sí i lẹ́nu. Lẹ́yìn tí Jesu ti gba ọtí náà tán, ó wí pé, “Ó ti parí!” Lẹ́yìn náà ó tẹrí ba, ó bá dákẹ́. Nítorí ọjọ́ náà jẹ́ ìpalẹ̀mọ́ Àjọ̀dún Ìrékọjá, kí òkú má baà wà lórí agbelebu ní Ọjọ́ Ìsinmi, àwọn Juu bẹ Pilatu pé kí ó jẹ́ kí wọ́n dá àwọn tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu ní ojúgun, kí wọ́n gbé wọn kúrò lórí agbelebu nítorí pé Ọjọ́ Ìsinmi pataki ni Ọjọ́ Ìsinmi náà. Àwọn ọmọ-ogun bá lọ, wọ́n dá ekinni-keji àwọn tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu pẹlu Jesu lójúgun. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu wọ́n rí i pé ó ti kú, nítorí náà wọn kò dá a lójúgun. Ṣugbọn ọmọ-ogun kan fi ọ̀kọ̀ gún un lẹ́gbẹ̀ẹ́, ẹ̀jẹ̀ ati omi bá tú jáde. (Ẹni tí ọ̀rọ̀ yìí ṣe ojú rẹ̀ ni ó jẹ́rìí, òtítọ́ ni ẹ̀rí rẹ̀, ó mọ̀ pé òtítọ́ ni òun sọ, kí ẹ̀yin lè gbàgbọ́.) Gbogbo èyí rí bẹ́ẹ̀ kí Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ tí ó wí pé, “Kò sí egungun rẹ̀ kan tí wọ́n ṣẹ́.” Ìwé Mímọ́ tún wí níbòmíràn pé, “Wọn yóo wo ẹni tí wọ́n fi ọ̀kọ̀ gún.” Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ wọnyi, Josẹfu ará Arimatia bẹ Pilatu pé kí ó jẹ́ kí òun gbé òkú Jesu lọ. Josẹfu yìí jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu tí ó fara pamọ́ nítorí ó bẹ̀rù àwọn Juu. Pilatu bá fún un ní àṣẹ láti gbé òkú Jesu. Ó bá lọ gbé e. Nikodemu, tí ó fòru bojú lọ sọ́dọ̀ Jesu nígbà kan rí, mú àdàlú òróró olóòórùn dídùn olówó iyebíye oríṣìí meji wá, wíwúwo rẹ̀ tó ọgbọ̀n kilogiramu. Wọ́n fi òróró yìí tọ́jú òkú Jesu, wọ́n bá wé e ní aṣọ-ọ̀gbọ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣà ìsìnkú àwọn Juu. Ọgbà kan wà níbi tí wọ́n ti kan Jesu mọ́ agbelebu. Ibojì titun kán wà ninu ọgbà náà, wọn kò ì tíì sin òkú kankan sinu rẹ̀ rí. Wọ́n tẹ́ òkú Jesu sibẹ, nítorí ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ àwọn Juu ni, ati pé ibojì náà súnmọ́ tòsí. Ní kutukutu ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, kí ilẹ̀ tó mọ́, Maria Magidaleni lọ sí ibojì náà, ó rí i pé wọ́n ti yí òkúta kúrò lẹ́nu rẹ̀. Ó bá sáré lọ sọ́dọ̀ Simoni Peteru ati ọmọ-ẹ̀yìn tí Jesu fẹ́ràn, ó sọ fún wọn pé, “Wọ́n ti gbé Oluwa kúrò ninu ibojì, a kò sì mọ ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.” Peteru ati ọmọ-ẹ̀yìn náà bá jáde, wọ́n lọ sí ibojì náà. Àwọn mejeeji bẹ̀rẹ̀ sí sáré; ṣugbọn ọmọ-ẹ̀yìn keji ya Peteru sílẹ̀, òun ni ó kọ́ dé ibojì. Ó bẹ̀rẹ̀ ó yọjú wo inú ibojì, ó rí aṣọ-ọ̀gbọ̀ tí ó wà nílẹ̀, ṣugbọn kò wọ inú ibojì. Nígbà tí Simoni Peteru tí ó tẹ̀lé e dé, ó wọ inú ibojì lọ tààrà. Ó rí aṣọ-ọ̀gbọ̀ nílẹ̀, ó rí aṣọ tí wọ́n fi wé orí òkú lọ́tọ̀, kò sí lára aṣọ-ọ̀gbọ̀, ó dá wà níbìkan ní wíwé. Ọmọ-ẹ̀yìn keji tí ó kọ́kọ́ dé ẹnu ibojì náà bá wọ inú ibojì; òun náà rí i, ó wá gbàgbọ́. (Nítorí ohun tí Ìwé Mímọ́ wí kò tíì yé wọn pé dandan ni kí ó jí dìde ninu òkú.) Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bá tún pada lọ sí ilé wọn. Ṣugbọn Maria dúró lóde lẹ́bàá ibojì, ó ń sunkún. Bí ó ti ń sunkún, ó bẹ̀rẹ̀ ó yọjú wo inú ibojì, ó bá rí àwọn angẹli meji tí wọ́n wọ aṣọ funfun, ọ̀kan jókòó níbi orí, ekeji jókòó níbi ẹsẹ̀ ibi tí wọ́n tẹ́ òkú Jesu sí. Wọ́n bi í pé, “Obinrin, kí ló dé tí ò ń sunkún?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Wọ́n ti gbé Oluwa mi lọ, n kò mọ ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.” Bí ó ti sọ báyìí tán, ó bojú wẹ̀yìn, ó bá rí Jesu tí ó dúró, ṣugbọn kò mọ̀ pé òun ni. Jesu bi í pé, “Obinrin, kí ní dé tí ò ń sunkún? Ta ni ò ń wá?” Maria ṣebí olùṣọ́gbà ni. Ó sọ fún un pé, “Alàgbà, bí o bá ti gbé e lọ, sọ ibi tí o tẹ́ ẹ sí fún mi, kí n lè lọ gbé e.” Jesu bá pè é lórúkọ, ó ní, “Maria!” Maria bá yipada sí i, ó pè é ní èdè Heberu pé, “Raboni!” (Ìtumọ̀ èyí ni “Olùkọ́ni.”) Jesu bá sọ fún un pé, “Mú ọwọ́ kúrò lára mi, nítorí n kò ì tíì gòkè tọ Baba mi lọ. Ṣugbọn lọ sọ́dọ̀ àwọn arakunrin mi, kí o sọ fún wọn pé, ‘Mò ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba mi ati Baba yín, Ọlọrun mi ati Ọlọrun yín.’ ” Maria Magidaleni bá lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Mo ti rí Oluwa!” Ó bá sọ ohun tí Jesu sọ fún un fún wọn. Nígbà tí ó di alẹ́ ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, níbi tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wà, tí wọ́n ti ìlẹ̀kùn mọ́rí nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn Juu, Jesu dé, ó dúró láàrin wọn. Ó kí wọn pé, “Alaafia fun yín!” Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, ó fi ọwọ́ rẹ̀ ati ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ hàn wọ́n. Ó tún kí wọn pé, “Alaafia fún yín! Gẹ́gẹ́ bí baba ti rán mi níṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni mo rán yín.” Lẹ́yìn tí ó sọ bẹ́ẹ̀ tán, ó mí sí wọn, ó bá wí fún wọn pé, “Ẹ gba Ẹ̀mí Mímọ́. Àwọn ẹni tí ẹ bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì, Ọlọrun dáríjì wọ́n. Àwọn ẹni tí ẹ kò bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì, Ọlọrun kò dáríjì wọ́n.” Ṣugbọn Tomasi, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila tí wọn ń pè ní Didimu (èyí ni “Ìbejì”) kò sí láàrin àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nígbà tí Jesu farahàn wọ́n. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yòókù sọ fún un pé, “Àwa ti rí Oluwa!” Ṣugbọn ó sọ fún wọn pé, “Bí n kò bá rí àpá ìṣó ní ọwọ́ rẹ̀, kí n fi ìka mi kan ibi tí àpá ìṣó wọ̀n-ọn-nì wà, kí n fi ọwọ́ mi kan ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, n kò ní gbàgbọ́!” Lẹ́yìn ọjọ́ mẹjọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tún wà ninu ilé, Tomasi náà wà láàrin wọn. Ìlẹ̀kùn wà ní títì bẹ́ẹ̀ ni Jesu bá tún dé, ó dúró láàrin wọn, ó ní, “Alaafia fun yín!” Ó wá wí fún Tomasi pé, “Mú ìka rẹ wá, wo ọwọ́ mi, mú ọwọ́ rẹ wá kí o fi kan ẹ̀gbẹ́ mi. Má ṣe alaigbagbọ mọ́, ṣugbọn gbàgbọ́.” Tomasi dá a lóhùn pé, “Oluwa mi ati Ọlọrun mi!” Jesu wí fún un pé, “O wá gbàgbọ́ nítorí o rí mi! Àwọn tí ó gbàgbọ́ láì rí mi ṣe oríire!” Ọpọlọpọ nǹkan ati iṣẹ́ abàmì mìíràn ni Jesu ṣe lójú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tí a kò kọ sinu ìwé yìí. Ṣugbọn a kọ ìwọ̀nyí kí ẹ lè gbàgbọ́ pé Jesu ni Mesaya, Ọmọ Ọlọrun, ati pé tí ẹ bá gbàgbọ́, kí ẹ lè ní ìyè ní orúkọ rẹ̀. Lẹ́yìn èyí, Jesu tún fara han àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ní òkun Tiberiasi. Bí ó ṣe farahàn wọ́n nìyí: Simoni Peteru, ati Tomasi tí wọn ń pè ní Didimu (èyí ni “Ìbejì”) ati Nataniẹli ará Kana, ni ilẹ̀ Galili, ati àwọn ọmọ Sebede ati àwọn meji mìíràn ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wà ní ibìkan. Simoni Peteru sọ fún wọn pé, “Mò ń lọ pa ẹja.” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwa náà yóo bá ọ lọ.” Wọ́n bá jáde lọ, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi. Ní gbogbo alẹ́ ọjọ́ náà wọn kò rí ẹja kankan pa. Nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́jú Jesu dúró ní èbúté, ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kò mọ̀ pé Jesu ni. Jesu bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ọmọde, ǹjẹ́ ẹ ní ohunkohun fún jíjẹ?” Wọ́n bá dá a lóhùn pé, “Rárá o!” Ó wí fún wọn pé, “Ẹ ju àwọ̀n sí apá ọ̀tún ọkọ̀, ẹ óo rí ẹja pa.” Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, ni wọn kò bá lè fa àwọ̀n mọ́, nítorí ọ̀pọ̀ ẹja. Ọmọ-ẹ̀yìn tí Jesu fẹ́ràn sọ fún Peteru pé, “Oluwa ni!” Nígbà tí Simoni Peteru gbọ́ pé Oluwa ni, ó wọ ẹ̀wù rẹ̀, nítorí ó ti bọ́ra sílẹ̀ fún iṣẹ́, ó bá bẹ́ sinu òkun, ó ń lúwẹ̀ẹ́ lọ sébùúté. Ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yòókù ń bọ̀ ninu ọkọ̀, nítorí wọn kò jìnnà sí èbúté, wọn kò jù bí ìwọ̀n ọgọrun-un ìgbésẹ̀ lọ. Nígbà tí wọ́n gúnlẹ̀, wọ́n rí ẹja lórí iná eléèédú, wọ́n tún rí burẹdi. Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ mú wá ninu ẹja tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ pa.” Nígbà náà ni Simoni Peteru gòkè, ó fa àwọ̀n sí èbúté. Àwọ̀n náà kún fún ẹja ńláńlá, mẹtalelaadọjọ. Ṣugbọn bí wọ́n ti pọ̀ tó yìí, àwọ̀n náà kò ya. Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ wá jẹun.” Kò sí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí ó bi í pé, “Ta ni ọ́?” Wọ́n mọ̀ pé Oluwa ni. Jesu wá, ó mú burẹdi, ó fi fún wọn. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó fún wọn ní ẹja jẹ. Èyí ni ó di ìgbà kẹta tí Jesu fara han àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lẹ́yìn ajinde rẹ̀ ninu òkú. Nígbà tí wọ́n jẹun tán, Jesu bi Simoni Peteru pé, “Simoni ọmọ Johanu, ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi ju àwọn wọnyi lọ?” Peteru dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa, o mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.” Jesu wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn ọ̀dọ́ aguntan mi.” Jesu tún bi í lẹẹkeji pé, “Simoni ọmọ Johanu, ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi?” Ó tún dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Oluwa, o mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.” Jesu wí fún un pé, “Máa tọ́jú àwọn aguntan mi.” Jesu tún bi í ní ẹẹkẹta pé, “Simoni ọmọ Johanu, ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi?” Ó dun Peteru nítorí Jesu bi í ní ẹẹkẹta pé, “Ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi?” Ó wá sọ fún Jesu pé, “Oluwa, o mọ ohun gbogbo, o mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.” Jesu sọ fún un pé, “Máa bọ́ àwọn aguntan mi. Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé nígbà tí o wà ní ọ̀dọ́, ò ń di ara rẹ ni àmùrè gírí, ò ń lọ sí ibi tí o bá fẹ́. Ṣugbọn nígbà tí o bá di arúgbó, ìwọ yóo na ọwọ́ rẹ, ẹlòmíràn yóo wọ aṣọ fún ọ, yóo fà ọ́ lọ sí ibi tí o kò fẹ́ lọ.” (Jesu sọ èyí bí àkàwé irú ikú tí Peteru yóo fi yin Ọlọrun lógo.) Nígbà tí Jesu sọ báyìí tán, ó wí fún un pé, “Máa tẹ̀lé mi.” Nígbà tí Peteru bojú wẹ̀yìn, ó rí ọmọ-ẹ̀yìn tí Jesu fẹ́ràn tí ó ń tẹ̀lé e. Òun ni ó súnmọ́ Jesu pẹ́kípẹ́kí nígbà tí wọn ń jẹun, tí ó bi Jesu pé, “Oluwa, ta ni yóo fi ọ́ lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ rí?” Nígbà tí Peteru rí i, ó bi Jesu pé, “Oluwa, eléyìí ńkọ́?” Jesu dá a lóhùn pé, “Bí mo bá fẹ́ kí ó wà títí n óo fi dé, èwo ni ó kàn ọ́? Ìwọ sá máa tẹ̀lé mi ní tìrẹ.” Nígbà tí gbolohun yìí dé etí àwọn onigbagbọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé ọmọ-ẹ̀yìn náà kò ní kú. Ṣugbọn kò sọ fún un pé kò ní kú. Ohun tí ó wí ni pé, “Bí mo bá fẹ́ kí ó wà títí n óo fi dé, èwo ni ó kàn ọ́?” Ọmọ-ẹ̀yìn náà ni ó jẹ́rìí sí nǹkan wọnyi. Òun ni ó kọ nǹkan wọnyi: a mọ̀ pé òtítọ́ ni ẹ̀rí rẹ̀. Ọpọlọpọ nǹkan mìíràn ni Jesu ṣe, bí a bá kọ wọ́n ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, mo rò pé kò ní sí ààyè tó ní gbogbo ayé tí yóo gba ìwé tí a bá kọ wọ́n sí. Tiofilu mi ọ̀wọ́n: Ninu ìwé mi àkọ́kọ́, mo ti sọ nípa gbogbo ohun tí Jesu ṣe ati ẹ̀kọ́ tí ó ń kọ́ àwọn eniyan, títí di ọjọ́ tí a gbé e lọ sókè ọ̀run lẹ́yìn tí ó ti pàṣẹ ohun tí ó fẹ́, nípa Ẹ̀mí Mímọ́, fún àwọn aposteli tí ó ti yàn. Àwọn aposteli yìí ni ó fi ara rẹ̀ hàn láàyè lẹ́yìn ìjìyà rẹ̀ pẹlu ẹ̀rí tí ó dájú. Wọ́n rí i níwọ̀n ogoji ọjọ́, ó sì ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tí ó jẹ mọ́ ti ìjọba Ọlọrun. Nígbà tí ó wà lọ́dọ̀ wọn, ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọn má kúrò ní Jerusalẹmu. Ó ní, “Ẹ dúró títí ìlérí tí Baba mí ṣe yóo fi ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gbọ́ tí mo sọ fun yín. Nítorí omi ni Johanu fi ń ṣe ìwẹ̀mọ́, ṣugbọn Ẹ̀mí Mímọ́ ni a óo fi ṣe ìwẹ̀mọ́ fun yín láìpẹ́ jọjọ.” Ní ọjọ́ kan tí gbogbo wọn péjọ, wọ́n bi í pé, “Oluwa, ṣé àkókò tó nisinsinyii tí ìwọ yóo gba ìjọba pada fún Israẹli?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Kì í ṣe tiyín láti mọ àkókò tabi ìgbà tí Baba ti fi sí ìkáwọ́ ara rẹ̀ nìkan ṣoṣo. Ṣugbọn ẹ̀yin yóo gba agbára nígbà tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé yin. Ẹ óo wá máa ṣe ẹlẹ́rìí mi ní Jerusalẹmu, ati ní gbogbo Judia ati ní Samaria ati títí dé òpin ilẹ̀ ayé.” Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, bí wọ́n ti ń wò ó, a gbé e sókè, ìkùukùu bò ó, wọn kò sì rí i mọ́. Bí wọ́n ti tẹjú mọ́ òkè bí ó ti ń lọ, àwọn ọkunrin meji tí wọ́n wọ aṣọ funfun dúró tì wọ́n. Wọ́n ní, “Ẹ̀yin ará Galili, kí ló dé tí ẹ fi dúró tí ẹ̀ ń wòkè bẹ́ẹ̀? Jesu kan náà, tí a mú kúrò lọ́dọ̀ yín, lọ sí ọ̀run yìí, yóo tún pada wá bí ẹ ṣe rí i tí ó ń lọ sí ọ̀run.” Wọ́n pada sí Jerusalẹmu láti orí òkè tí à ń pè ní Òkè Olifi. Òkè náà súnmọ́ Jerusalẹmu, kò tó ibùsọ̀ kan sí ìlú. Nígbà tí wọ́n wọ inú ilé, wọ́n lọ sí iyàrá òkè níbi tí wọn ń gbé. Àwọn tí wọ́n jọ ń gbé ni Peteru, Johanu, Jakọbu, Anderu, Filipi, Tomasi, Batolomiu, Matiu, Jakọbu ọmọ Alfeu, Simoni ti ẹgbẹ́ Seloti ati Judasi ọmọ Jakọbu. Gbogbo wọn ń fi ọkàn kan gbadura nígbà gbogbo pẹlu àwọn obinrin ati Maria ìyá Jesu ati àwọn arakunrin Jesu. Ní ọjọ́ kan, Peteru dìde láàrin àwọn arakunrin tí wọ́n tó ọgọfa eniyan, ó ní, “Ẹ̀yin ará, dandan ni pé kí ohun tí Ẹ̀mí Mímọ́ sọ ninu Ìwé Mímọ́ láti ẹnu Dafidi ṣẹ, nípa ọ̀rọ̀ Judasi tí ó ṣe amọ̀nà àwọn tí ó mú Jesu. Nítorí ọ̀kan ninu wa ni, ó sì ní ìpín ninu iṣẹ́ yìí.” (Ó ra ilẹ̀ kan pẹlu owó tí ó gbà fún ìwà burúkú rẹ̀, ni ó bá ṣubú lulẹ̀, ikùn rẹ̀ sì bẹ́, gbogbo ìfun rẹ̀ bá tú jáde. Gbogbo àwọn eniyan tí ó ń gbé Jerusalẹmu ni ó mọ̀ nípa èyí. Wọ́n bá ń pe ilẹ̀ náà ní “Akelidama” ní èdè wọn. Ìtumọ̀ èyí ni “Ilẹ̀ Ẹ̀jẹ̀.”) “Ọ̀rọ̀ náà rí bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ninu Ìwé Orin Dafidi pé, ‘Kí ibùgbé rẹ̀ di ahoro, kí ẹnikẹ́ni má gbé ibẹ̀.’ Ati pé, ‘Kí á fi ipò rẹ̀ fún ẹlòmíràn.’ “Nítorí náà, ẹ̀tọ́ ni kí á yan ẹnìkan ninu àwọn tí ó ti wà pẹlu wa ní gbogbo àkókò tí Jesu Oluwa ti ń wọlé, tí ó ń jáde pẹlu wa, láti àkókò tí Johanu ti ń ṣe ìrìbọmi títí di ọjọ́ tí a fi mú Jesu kúrò lọ́dọ̀ wa, kí olúwarẹ̀ lè jẹ́ ẹlẹ́rìí ajinde Jesu, kí ó sì di ọ̀kan ninu wa.” *** Wọ́n bá gbé ẹni meji siwaju: Josẹfu tí à ń pè ní Basaba, tí ó tún ń jẹ́ Jusitu, ati Matiasi. Wọ́n gbadura pé, “Ìwọ Oluwa, Olùmọ̀ràn gbogbo eniyan, fi ẹni tí o bá yàn ninu àwọn mejeeji yìí hàn, kí ó lè gba iṣẹ́ yìí ati ipò aposteli tí Judasi fi sílẹ̀ láti lọ sí ààyè tirẹ̀.” Wọ́n bá ṣẹ́ gègé. Gègé bá mú Matiasi. Ó bá di ọ̀kan ninu àwọn aposteli mọkanla. Ní ọjọ́ Pẹntikọsti, gbogbo wọn wà pọ̀ ní ibìkan náà. Lójijì ìró kan dún láti ọ̀run, ó dàbí ìgbà tí afẹ́fẹ́ líle bá ń fẹ́, ó sì kún gbogbo inú ilé níbi tí wọ́n gbé jókòó. Wọ́n rí nǹkankan tí ó dàbí ahọ́n iná, tí ó pín ara rẹ̀, tí ó sì bà lé ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn. Gbogbo wọn bá kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí sọ oríṣìíríṣìí èdè mìíràn gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí ti fi fún wọn láti máa sọ. Ní àkókò náà, àwọn Juu tí wọ́n jẹ́ olùfọkànsìn ti gbogbo orílẹ̀-èdè ayé wá, wọ́n wà ní Jerusalẹmu. Nígbà tí wọ́n gbọ́ ìró yìí, àwọn eniyan rọ́ wá. Ẹnu yà wọ́n nítorí ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn gbọ́ tí wọn ń sọ èdè tirẹ̀. Èyí dà wọ́n láàmú, ó sì yà wọ́n lẹ́nu. Wọ́n ní, “Ṣebí ará Galili ni gbogbo àwọn tí ó ń sọ̀rọ̀ wọnyi? Kí ló dé tí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa fi gbọ́ tí wọn ń sọ èdè abínibí rẹ̀? Ati ará Patia, ati ará Media ati ará Elamu; àwọn tí ó ń gbé ilẹ̀ Mesopotamia, ilẹ̀ Judia ati ilẹ̀ Kapadokia; ilẹ̀ Pọntu, ilẹ̀ Esia, ilẹ̀ Firigia ati ilẹ̀ Pamfilia; ilẹ̀ Ijipti ati agbègbè Libia lẹ́bàá Kirene; àwọn àlejò láti ìlú Romu, àwọn Juu ati àwọn aláwọ̀ṣe ẹ̀sìn Juu; àwọn ará Kirete ati àwọn ará Arabia, gbogbo wa ni a gbọ́ tí wọ́n ń sọ àwọn iṣẹ́ ńlá Ọlọrun ní oríṣìíríṣìí èdè wa.” Ìdààmú bá gbogbo àwọn eniyan, ó pá wọn láyà. Wọ́n ń bi ara wọn pé, “Kí ni ìtumọ̀ èyí?” Ṣugbọn àwọn mìíràn ń ṣe ẹlẹ́yà; wọ́n ní, “Wọ́n ti mu ọtí yó ni!” Peteru wá dìde dúró pẹlu àwọn aposteli mọkanla, ó sọ̀rọ̀ sókè, ó ní, “Ẹ̀yin ará, ẹ̀yin Juu, ati gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí ye yín, kí ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi. Àwọn yìí kò mutí yó bí ẹ ti rò, nítorí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ di agogo mẹsan-an òwúrọ̀ ni. Ṣugbọn ohun tí Joẹli, wolii Ọlọrun ti sọ wá ṣẹ lónìí, tí ó wí pé, ‘Ọlọrun sọ pé, “Nígbà tí ó bá di àkókò ìkẹyìn, n óo tú Ẹ̀mí mi jáde sórí gbogbo eniyan. Àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin yóo sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ọdọmọkunrin yín yóo rí ìran, àwọn àgbà yín yóo sì lá àlá. Àní, ní àkókò náà, n óo tú Ẹ̀mí mi sórí àwọn ẹrukunrin mi ati sí orí àwọn ẹrubinrin mi, àwọn náà yóo sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀. N óo fi ohun ìyanu hàn lókè ọ̀run, ati ohun abàmì lórí ilẹ̀ ayé; ẹ̀jẹ̀, ati iná, ìkùukùu ati èéfín. Oòrùn yóo ṣókùnkùn, òṣùpá yóo di ẹ̀jẹ̀, kí ó tó di ọjọ́ ńlá tí ó lókìkí, ọjọ́ Oluwa. Ní ọjọ́ náà gbogbo ẹni tí ó bá ké pe orúkọ Oluwa ni a óo gbà là.” ’ “Ẹ̀yin ará, ọmọ Israẹli, ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi. Jesu ará Nasarẹti ni ẹni tí Ọlọrun ti fihàn fun yín pẹlu iṣẹ́ agbára, iṣẹ́ ìyanu, iṣẹ́ abàmì tí Ọlọrun ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe láàrin yín. Ẹ̀yin fúnra yín sì mọ̀ bẹ́ẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọrun ati ètò tí Ọlọrun ti ṣe tẹ́lẹ̀, a fi í le yín lọ́wọ́, ẹ jẹ́ kí àwọn aláìbìkítà fún Òfin kàn án mọ́ agbelebu, ẹ sì pa á. Ṣugbọn Ọlọrun tú ìdè ikú, ó jí i dìde ninu òkú! Kò jẹ́ kí ikú ní agbára lórí rẹ̀. Nítorí Dafidi sọ nípa rẹ̀ pé, ‘Mo rí Oluwa níwájú mi nígbà gbogbo, ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi nítorí náà ohunkohun kò lè dà mí láàmú. Nítorí náà inú mi dùn, mo bú sẹ́rìn-ín. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé eniyan ẹlẹ́ran-ara ni mí, sibẹ n óo gbé ìgbé-ayé mi pẹlu ìrètí; nítorí o kò ní fi ọkàn mi sílẹ̀ ní ibùgbé àwọn òkú; bẹ́ẹ̀ ni o kò ní jẹ́ kí ẹni mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́. O ti fi ọ̀nà ìyè hàn mí, O óo sì fi ayọ̀ kún ọkàn mi níwájú rẹ.’ “Ẹ̀yin ará, mo sọ fun yín láìṣe àní-àní pé Dafidi baba-ńlá wa kú, a sì sin ín; ibojì rẹ̀ wà níhìn-ín títí di òní. Ṣugbọn nítorí ó jẹ́ aríran, ó sì mọ̀ pé Ọlọrun ti búra fún òun pé ọ̀kan ninu ọmọ tí òun óo bí ni yóo jókòó lórí ìtẹ́ òun, ó ti rí i tẹ́lẹ̀ pé Mesaya yóo jí dìde kúrò ninu òkú. Ìdí nìyí tí ó fi sọ pé, ‘A kò fi í sílẹ̀ ní ibùgbé àwọn òkú; bẹ́ẹ̀ ni ẹran-ara rẹ̀ kò díbàjẹ́.’ Jesu yìí ni Ọlọrun jí dìde. Gbogbo àwa yìí sì ni ẹlẹ́rìí. Nisinsinyii tí a ti gbé e ka ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun, ó ti gba ìlérí Ẹ̀mí Mímọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba, ó wá tú u jáde. Ohun tí ẹ̀ ń rí, tí ẹ sì ń gbọ́ nìyí. Nítorí Dafidi kò gòkè lọ sí ọ̀run. Ohun tí Dafidi sọ ni pé, ‘Oluwa wí fún oluwa mi pé: Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi títí n óo fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di tìmùtìmù ìtìsẹ̀ rẹ.’ “Nítorí náà kí gbogbo ilé Israẹli mọ̀ dájú pé Jesu yìí tí ẹ̀yin kàn mọ́ agbelebu ni Ọlọrun ti fi ṣe Oluwa ati Mesaya!” Nígbà tí àwọn eniyan gbọ́, ọ̀rọ̀ náà gún wọn lọ́kàn. Wọ́n wá bi Peteru ati àwọn aposteli yòókù pé, “Ẹ̀yin ará, kí ni kí á wá ṣe?” Peteru dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ronupiwada, kí á ṣe ìrìbọmi fún ẹnìkọ̀ọ̀kan yín ní orúkọ Kristi. A óo sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín, ẹ óo wá gba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́. Nítorí ẹ̀yin ni a ṣe ìlérí yìí fún, ati àwọn ọmọ yín ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ọ̀nà jíjìn; a ṣe é fún gbogbo ẹni tí Oluwa Ọlọrun wa bá pè.” Ó tún bá wọn sọ̀rọ̀ pupọ, ó ń rọ̀ wọ́n gidigidi, pé, “Ẹ gba ara yín kúrò ninu ìyà tí ìran burúkú yìí yóo jẹ.” A ṣe ìrìbọmi fún àwọn tí wọ́n gba ọ̀rọ̀ náà. Ní ọjọ́ náà àwọn ẹgbẹẹdogun (3,000) eniyan ni a kà kún ọmọ ìjọ. Wọ́n ń fi tọkàntọkàn kọ́ ẹ̀kọ́ tí àwọn aposteli ń kọ́ wọn; wọ́n wà ní ìrẹ́pọ̀, wọ́n jọ ń jẹun; wọ́n jọ ń gbadura. Ẹ̀rù àwọn onigbagbọ wá ń ba gbogbo eniyan. Ọpọlọpọ ni iṣẹ́ ìyanu ati iṣẹ́ abàmì tí a ti ọwọ́ àwọn aposteli ṣe. Gbogbo àwọn onigbagbọ wà ní ibìkan náà. Wọ́n jọ ní ohun gbogbo ní àpapọ̀. Wọ́n ta gbogbo ohun tí wọ́n ní, wọ́n sì pín owó tí wọ́n rí láàrin ara wọn, gẹ́gẹ́ bí ẹnìkọ̀ọ̀kan ti ṣe aláìní sí. Wọ́n ń fi ọkàn kan lọ sí Tẹmpili lojoojumọ. Wọ́n jọ ń jẹun láti ilé dé ilé. Wọ́n jọ ń jẹun pẹlu ayọ̀ ati pẹlu ọkàn kan. Wọ́n ń fi ìyìn fún Ọlọrun. Gbogbo àwọn eniyan ni ó fẹ́ràn wọn. Lojoojumọ ni àwọn tí wọ́n rí ìgbàlà ń dara pọ̀ mọ́ wọn. Ní agogo mẹta ọ̀sán, Peteru ati Johanu gòkè lọ sí Tẹmpili ní àkókò adura. Ọkunrin kan wà tí wọn máa ń gbé wá sibẹ, tí ó yarọ láti inú ìyá rẹ̀ wá. Lojoojumọ, wọn á máa gbé e wá sí ẹnu ọ̀nà Tẹmpili tí à ń pè ní “Ẹnu Ọ̀nà Dáradára,” kí ó lè máa ṣagbe lọ́dọ̀ àwọn tí ń wọ inú Tẹmpili lọ. Nígbà tí ó rí Peteru ati Johanu tí wọ́n fẹ́ wọ inú Tẹmpili, ó ní kí wọ́n ta òun lọ́rẹ. Peteru ati Johanu tẹjú mọ́ ọn, Peteru ní, “Wò wá!” Ọkunrin náà bá ń wò wọ́n, ó ń retí pé wọn yóo fún òun ní nǹkan. Peteru bá sọ fún un pé, “N kò ní fadaka tabi wúrà, ṣugbọn n óo fún ọ ní ohun tí mo ní. Ní orúkọ Jesu Kristi ti Nasarẹti, máa rìn.” Ó bá fà á lọ́wọ́ ọ̀tún, ó gbé e dìde. Lẹsẹkẹsẹ ẹsẹ̀ rẹ̀ ati ọrùn-ẹsẹ̀ rẹ̀ bá mókun. Ó bá fò sókè, ó dúró, ó sì ń rìn. Ó bá tẹ̀lé wọn wọ inú Tẹmpili; ó ń rìn, ó ń fò sókè, ó sì ń yin Ọlọrun. Gbogbo àwọn eniyan rí i tí ó ń rìn, tí ó ń yin Ọlọrun. Wọ́n ṣe akiyesi pé ẹni tí ó ti máa ń jókòó ṣagbe lẹ́nu Ọ̀nà Dáradára Tẹmpili ni. Ẹnu yà wọ́n, wọ́n ta gìrì sí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọkunrin náà. Bí ọkunrin náà ti rọ̀ mọ́ Peteru ati Johanu, gbogbo àwọn eniyan sáré pẹlu ìyanu lọ sọ́dọ̀ wọn ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ tí à ń pè ní ti Solomoni. Nígbà tí Peteru rí wọn, ó bi àwọn eniyan pé, “Ẹ̀yin eniyan Israẹli, kí ló dé tí èyí fi yà yín lẹ́nu? Kí ló dé tí ẹ fi tẹjú mọ́ wa bí ẹni pé nípa agbára wa tabi nítorí pé a jẹ́ olùfọkànsìn ni a fi mú kí ọkunrin yìí rìn? Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu, Ọlọrun àwọn baba wa ni ó dá Ọmọ rẹ̀, Jesu lọ́lá. Jesu yìí ni ẹ fi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, òun ni ẹ sẹ́ níwájú Pilatu nígbà tí ó fi dá a sílẹ̀. Ẹ sẹ́ ẹni Ọlọrun ati olódodo, ẹ wá bèèrè pé kí wọ́n dá apànìyàn sílẹ̀ fun yín; ẹ pa orísun ìyè. Òun yìí ni Ọlọrun jí dìde kúrò ninu òkú. Àwa gan-an ni ẹlẹ́rìí pé bẹ́ẹ̀ ló rí. Orúkọ Jesu ati igbagbọ ninu orúkọ yìí ni ó mú ọkunrin tí ẹ rí yìí lára dá. Ẹ ṣá mọ̀ ọ́n. Igbagbọ ninu rẹ̀ ni ó fún ọkunrin yìí ní ìlera patapata, gẹ́gẹ́ bí gbogbo yín ti rí i fúnra yín. “Ṣugbọn nisinsinyii, ará, mo mọ̀ pé ẹ kò mọ̀ọ́nmọ̀ ṣe é, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìjòyè yín náà kò mọ̀ọ́nmọ̀ ṣe é. Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun ṣe mú ohun tí ó ti sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu gbogbo àwọn wolii rẹ̀ ṣẹ, pé Mesaya òun níláti jìyà. Nítorí náà, ẹ ronupiwada, kí ẹ yipada sọ́dọ̀ Ọlọrun bí ẹ bá fẹ́ kí á pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́. Nígbà náà, àkókò ìtura láti ọ̀dọ̀ Oluwa, yóo dé ba yín; Oluwa yóo wá rán Mesaya tí ó ti yàn tẹ́lẹ̀ si yín, èyí nnì ni Jesu, ẹni tí ó níláti wà ní ọ̀run títí di àkókò tí ohun gbogbo yóo fi di titun, gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti sọ láti ìgbà àtijọ́, láti ẹnu àwọn wolii rẹ̀ mímọ́, àwọn eniyan ọ̀tọ̀. Mose ṣá ti sọ pé, ‘Oluwa Ọlọrun yín yóo gbé wolii kan bí èmi dìde láàrin àwọn arakunrin yín. Òun ni kí ẹ gbọ́ràn sí lẹ́nu ninu ohun gbogbo tí ó bá sọ fun yín. Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbọ́ràn sí wolii náà lẹ́nu, píparun ni a óo pa á run patapata láàrin àwọn eniyan Ọlọrun.’ Gbogbo àwọn wolii, láti ìgbà Samuẹli ati àwọn tí ó dé lẹ́yìn rẹ̀, fi ohùn ṣọ̀kan sí ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n ń sọ nípa àkókò yìí. Ẹ̀yin gan-an ni ọmọ àwọn wolii; nítorí tiyín ni Ọlọrun ṣe bá àwọn baba yín dá majẹmu, nígbà tí ó sọ fún Abrahamu pé, ‘Nípa ọmọ rẹ ni n óo ṣe bukun gbogbo orílẹ̀-èdè ayé.’ Nígbà tí Ọlọrun gbé Ọmọ rẹ̀ dìde, ẹ̀yin ni ó kọ́kọ́ rán an sí, kí ó lè bukun yín láti mú kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yipada kúrò ní ọ̀nà burúkú rẹ̀.” Bí Peteru ti ń bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Johanu wà lọ́dọ̀ rẹ̀, àwọn alufaa ati olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ Tẹmpili ati àwọn Sadusi bá dé. Inú bí wọn nítorí wọ́n ń kọ́ àwọn eniyan pé àwọn òkú yóo jí dìde. Wọ́n fi ajinde ti Jesu ṣe àpẹẹrẹ. Wọ́n bá mú wọn, wọ́n tì wọ́n mọ́lé títí di ọjọ́ keji, nítorí ilẹ̀ ti ṣú. Ṣugbọn ọ̀pọ̀ ninu àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà gbàgbọ́, iye wọn tó ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) eniyan. Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, àwọn ìjòyè ati àwọn àgbààgbà ati àwọn amòfin péjọ ní Jerusalẹmu. Anasi Olórí Alufaa ati Kayafa ati Johanu ati Alẹkisanderu ati àwọn ìdílé Olórí Alufaa wà níbẹ̀. Wọ́n mú Peteru ati Johanu wá siwaju ìgbìmọ̀. Wọ́n wá bi wọ́n pé, “Irú agbára wo ni ẹ fi ṣe ohun tí ẹ ṣe yìí? Orúkọ ta ni ẹ lò?” Nígbà náà ni Ẹ̀mí Mímọ́ wá fún Peteru ní agbára lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, ó bá sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ìjòyè láàrin àwọn eniyan ati ẹyin àgbààgbà, bí ẹ bá ń wádìí lónìí nípa iṣẹ́ rere tí a ṣe fún ọkunrin aláìsàn yìí, bí ẹ bá fẹ́ mọ bí ara rẹ̀ ti ṣe dá, ẹ jẹ́ kí ó hàn sí gbogbo yín ati gbogbo eniyan Israẹli pé, ọkunrin yìí dúró níwájú yín pẹlu ara líle nítorí orúkọ Jesu Kristi ará Nasarẹti, ẹni tí ẹ kàn mọ́ agbelebu, tí Ọlọrun jí dìde kúrò ninu òkú. Jesu yìí ni ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀, tí ó wá di òkúta pataki igun-ilé.’ Kò sí ìgbàlà lọ́dọ̀ ẹlòmíràn; bẹ́ẹ̀ ni kò sí orúkọ mìíràn tí a fi fún eniyan lábẹ́ ọ̀run nípa èyí tí a lè fi gba eniyan là.” Nígbà tí wọ́n rí ìgboyà Peteru ati ti Johanu, tí wọ́n wòye pé wọn kò mọ ìwé àtipé òpè eniyan ni wọ́n, ẹnu yà wọ́n. Wọ́n ṣe akiyesi wọn pé wọ́n ti wà pẹlu Jesu. Wọ́n wo ọkunrin tí wọ́n mú lára dá tí ó dúró lọ́dọ̀ wọn, wọn kò sì mọ ohun tí wọn yóo sọ. Wọ́n bá pàṣẹ pé kí wọ́n jáde kúrò lọ́dọ̀ àwọn ìgbìmọ̀. Àwọn ìgbìmọ̀ wá ń bi ara wọn pé, “Kí ni a óo ṣe sí àwọn ọkunrin wọnyi o? Nítorí ó hàn lónìí sí gbogbo àwọn tí ó ń gbé Jerusalẹmu pé wọ́n ti ṣe iṣẹ́ abàmì. A kò sì lè wí pé èyí kò rí bẹ́ẹ̀. Ṣugbọn kí ó má baà tún máa tàn kálẹ̀ sí i láàrin àwọn eniyan, ẹ jẹ́ kí á kìlọ̀ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ dárúkọ Jesu fún ẹnikẹ́ni mọ́.” Àwọn ìgbìmọ̀ bá tún pè wọ́n wọlé, wọ́n pàṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ tún dárúkọ Jesu mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbọdọ̀ tún fi orúkọ Jesu kọ́ àwọn eniyan mọ́. Ṣugbọn Peteru ati Johanu dá wọn lóhùn pé, “Èwo ni ó tọ́ níwájú Ọlọrun: kí á gbọ́ràn si yín lẹ́nu ni, tabi kí á gbọ́ràn sí Ọlọrun lẹ́nu? Ẹ̀yin náà ẹ dà á rò. Ní tiwa, a kò lè ṣe aláìsọ ohun tí a ti rí ati ohun tí a ti gbọ́.” Lẹ́yìn tí wọ́n tún halẹ̀ mọ́ wọn, wọ́n dá wọn sílẹ̀, nítorí wọn kò rí ọ̀nà tí wọn ìbá fi jẹ wọ́n níyà, nítorí àwọn eniyan. Gbogbo eniyan ni wọ́n sì ń fi ìyìn fún Ọlọrun fún ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Ọkunrin tí wọn ṣe iṣẹ́ abàmì ìmúláradá yìí lára rẹ̀ ju ẹni ogoji ọdún lọ. Nígbà tí wọ́n dá wọn sílẹ̀, wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹgbẹ́ wọn, wọ́n ròyìn ohun gbogbo tí àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbààgbà sọ fún wọn. Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n jọ ké pe Ọlọrun pé, “Oluwa, ìwọ tí ó dá ọ̀run ati ayé ati òkun ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn, ìwọ tí ó sọ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ láti ẹnu baba ńlá wa, Dafidi, ọmọ rẹ pé, ‘Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń di rìkíṣí, tí àwọn ará ilẹ̀ òkèèrè ń gbèrò asán? Àwọn ọba ayé kó ara wọn jọ, àwọn ìjòyè fohùn ṣọ̀kan, láti dìtẹ̀ sí Oluwa ati sí Mesaya rẹ̀.’ Nítorí òdodo ni pé Hẹrọdu ati Pọntiu Pilatu pẹlu àwọn tí kì í ṣe Juu ati àwọn eniyan Israẹli péjọpọ̀ ní ìlú yìí, wọ́n ṣe ohun tí ó lòdì sí ọmọ mímọ́ rẹ, Jesu tí o ti fi òróró yàn ní Mesaya, àwọn ohun tí ọwọ́ rẹ ati ètò rẹ ti ṣe ìlànà rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Ǹjẹ́ nisinsinyii, Oluwa, ṣe akiyesi bí wọ́n ti ń halẹ̀, kí o sì fún àwọn iranṣẹ rẹ ní ìgboyà ní gbogbo ọ̀nà láti lè sọ ọ̀rọ̀ rẹ. Kí o wá na ọwọ́ rẹ kí o ṣe ìwòsàn, ṣe iṣẹ́ abàmì, ati iṣẹ́ ìyanu nípa orúkọ Jesu ọmọ mímọ́ rẹ.” Bí wọ́n ti ń gbadura, ibi tí wọ́n péjọ sí mì tìtì, gbogbo wọn bá kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọ́n bá ń fi ìgboyà sọ ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ọkàn kan ati ẹ̀mí kan ni gbogbo àwùjọ àwọn onigbagbọ ní. Kò sí ẹnìkan ninu wọn tí ó dá àwọn nǹkan tirẹ̀ yà sọ́tọ̀, wọ́n jọ ní gbogbo nǹkan papọ̀ ni. Àwọn aposteli ń fi ẹ̀rí wọn hàn pẹlu agbára ńlá nípa ajinde Jesu Oluwa. Gbogbo àwọn eniyan sì ń bọlá fún wọn. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó ṣe aláìní ohun kan láàrin wọn. Àwọn tí ó ní ilẹ̀ tabi ilé tà wọ́n, wọ́n mú owó tí wọ́n tà wọ́n wá, wọ́n dà á sílẹ̀ níwájú àwọn aposteli kí wọ́n lè pín in fún àwọn tí ó bá ṣe aláìní. Josẹfu, ọmọ ìdílé Lefi ará Kipru ẹni tí àwọn aposteli ń pè ní Banaba, (èyí ni “Ọmọ ìtùnú,”) ní ilẹ̀ kan. Ó tà á, ó sì mú owó rẹ̀ wá fún àwọn aposteli. Ọkunrin kan tí ń jẹ́ Anania pẹlu Safira, iyawo rẹ̀, ta ilẹ̀ kan. Ọkunrin yìí yọ sílẹ̀ ninu owó tí wọ́n rí lórí rẹ̀, ó bá mú ìyókù wá siwaju àwọn aposteli. Iyawo rẹ̀ sì mọ̀ nípa rẹ̀. Peteru bá bi í pé, “Anania, kí ló dé tí Satani fi gbà ọ́ lọ́kàn tí o fi ṣe èké sí Ẹ̀mí Mímọ́, tí o fi yọ sílẹ̀ ninu owó tí o rí lórí ilẹ̀ náà? Kí o tó ta ilẹ̀ náà, mo ṣebí tìrẹ ni? Nígbà tí o tà á tán, mo ṣebí o ní àṣẹ lórí owó tí o tà á? Kí ló dé tí o gbèrò irú nǹkan yìí? Kì í ṣe eniyan ni o ṣèké sí, Ọlọrun ni.” Nígbà tí Anania gbọ́ gbolohun yìí, ó ṣubú lulẹ̀, ó kú. Ẹ̀rù ńlá sì ba gbogbo àwọn tí wọ́n gbọ́. Àwọn géńdé bá dìde, wọ́n fi aṣọ wé e, wọ́n gbé e lọ sin. Nígbà tí ó tó bíi wakati mẹta lẹ́yìn náà, iyawo Anania wọlé dé. Kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Peteru bi í pé, “Sọ fún mi, ṣé iye tí ẹ ta ilẹ̀ náà nìyí?” Ó dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, iye tí a tà á ni.” Peteru bá bi í pé, “Kí ló dé tí ẹ jọ fi ohùn ṣọ̀kan láti dán Ẹ̀mí Oluwa wò? Wo ẹsẹ̀ àwọn tí wọ́n lọ sin ọkọ rẹ lẹ́nu ọ̀nà, wọn yóo gbé ìwọ náà jáde.” Ni òun náà bá ṣubú lulẹ̀ lẹsẹkẹsẹ níwájú Peteru, ó bá kú. Àwọn géńdé bá wọlé, wọ́n rí òkú rẹ̀. Wọ́n bá gbé e jáde, wọ́n sì sin ín sí ẹ̀bá ọkọ rẹ̀. Ẹ̀rù ńlá ba gbogbo ìjọ ati gbogbo àwọn tí ó gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ wọnyi. Ọpọlọpọ iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu ni àwọn aposteli ṣe láàrin àwọn eniyan. Gbogbo wọn wà ní ìṣọ̀kan ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ tí wọn ń pè ní ti Solomoni. Kò sí ẹni tí ó láyà ninu àwọn ìyókù láti darapọ̀ mọ́ wọn. Ọ̀rọ̀ wọn níyì lọ́dọ̀ àwọn eniyan. Àwọn tí wọ́n gba Oluwa gbọ́ túbọ̀ ń darapọ̀ mọ́ wọn, lọkunrin ati lobinrin. Nígbà tí ó yá, àwọn eniyan a máa gbé àwọn aláìsàn wá sí títì lórí ẹní ati lórí ibùsùn, pé kí òjìji Peteru lè ṣíji bò wọ́n nígbà tí ó bá ń kọjá. Ọpọlọpọ àwọn eniyan wá láti agbègbè ìlú Jerusalẹmu, wọ́n ń gbé àwọn aláìsàn ati àwọn tí ẹ̀mí burúkú ń dà láàmú wá; a sì mú gbogbo wọn lára dá. Nígbà náà ni ẹ̀tanú gba ọkàn Olórí Alufaa ati gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Sadusi tí ó wà pẹlu rẹ̀. Wọ́n bá mú àwọn aposteli, wọ́n tì wọ́n mọ́lé ninu ilé ẹ̀wọ̀n ìgboro ìlú. Nígbà tí ó di òru, angẹli Oluwa ṣí ìlẹ̀kùn ilé-ẹ̀wọ̀n, ó sìn wọ́n jáde, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ dúró ninu Tẹmpili kí ẹ sọ gbogbo ọ̀rọ̀ ìyè yìí fún àwọn eniyan.” Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n wọ inú Tẹmpili lọ nígbà tí ojúmọ́ mọ́, wọ́n bá ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tí Olórí Alufaa dé pẹlu àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ó pe ìgbìmọ̀ ati gbogbo àwọn àgbààgbà láàrin àwọn ọmọ Israẹli jọ. Wọ́n bá ranṣẹ lọ sí inú ẹ̀wọ̀n kí wọn lọ mú àwọn aposteli náà wá. Nígbà tí àwọn tí wọ́n rán dé ilé-ẹ̀wọ̀n, wọn kò rí wọn níbẹ̀. Wọ́n bá pada lọ jíṣẹ́ pé, “A fojú wa rí ilé-ẹ̀wọ̀n ní títì, a bá àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọ tí wọ́n dúró lẹ́nu ọ̀nà. Ṣugbọn nígbà tí a ṣílẹ̀kùn, tí a wọ inú ilé, a kò rí ẹnìkan.” Nígbà tí ọ̀gá àwọn ẹ̀ṣọ́ ti Tẹmpili ati àwọn olórí alufaa gbọ́ ìròyìn yìí, ọkàn wọn dàrú; wọ́n ń ronú pé, irú kí ni eléyìí? Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹnìkan bá dé, wọ́n sọ fún wọn pé, “Àwọn ọkunrin tí ẹ tì mọ́lé wà ninu Tẹmpili, tí wọn ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́.” Nígbà náà ni ọ̀gá àwọn ẹ̀ṣọ́ ati àwọn iranṣẹ lọ mú àwọn aposteli. Àwọn ẹ̀ṣọ́ náà kò fi ipá mú wọn, nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan kí àwọn eniyan má baà sọ wọ́n ní òkúta. Wọ́n mú wọn wá siwaju ìgbìmọ̀. Olórí Alufaa wá bi wọ́n pé, “Mo ṣebí a pàṣẹ fun yín pé kí ẹ má fi orúkọ yìí kọ́ ẹnikẹ́ni mọ́? Sibẹ gbogbo ará Jerusalẹmu ni ó ti gbọ́ nípa ẹ̀kọ́ yín yìí. Ẹ wá tún di ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ọkunrin yìí lé wa lórí?” Peteru pẹlu àwọn aposteli dáhùn pé, “A níláti gbọ́ ti Ọlọrun ju ti eniyan lọ. Jesu tí ẹ̀yin pa, tí ẹ kàn mọ́ igi, Ọlọrun àwọn baba wa jí i dìde. Òun ni Ọlọrun fi ṣe aṣiwaju ati olùgbàlà, tí ó gbé sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, kí ó lè fi anfaani ìrònúpìwàdà ati ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún Israẹli. Àwa gan-an ati Ẹ̀mí Mímọ́ tí Ọlọrun fi fún àwọn tí ó gbọ́ràn sí i lẹ́nu ni ẹlẹ́rìí àwọn ọ̀rọ̀ wọnyi.” Ọ̀rọ̀ yìí gún àwọn tí ó gbọ́ ọ lọ́kàn tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi fẹ́ pa wọ́n. Ṣugbọn Farisi kan ninu àwọn ìgbìmọ̀ dìde. Orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gamalieli, olùkọ́ nípa ti òfin ni, ó lókìkí láàrin gbogbo àwọn eniyan. Ó ní kí àwọn ọkunrin náà jáde fún ìgbà díẹ̀. Ó wá sọ fún àwọn ìgbìmọ̀ pé, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ ṣọ́ra nípa ohun tí ẹ fẹ́ ṣe sí àwọn ọkunrin yìí. Nítorí nígbà kan, Tudasi kan dìde. Ó ní òun jẹ́ eniyan ńlá kan. Ó kó àwọn eniyan bí irinwo (400) jọ. Nígbà tó yá wọ́n pa á, wọ́n sì tú gbogbo àwọn tí ó ń tẹ̀lé e ká; gbogbo ọ̀tẹ̀ rẹ̀ sì jásí òfo. Lẹ́yìn èyí, Judasi kan, ará Galili, dìde ní àkókò tí à ń kọ orúkọ àwọn eniyan sílẹ̀. Àwọn eniyan tẹ̀lé e. Ṣugbọn wọ́n pa á, wọ́n sì tú gbogbo àwọn tí ó ń tẹ̀lé e ká. To ò, mo sọ fun yín o! Ẹ gáfárà fún àwọn ọkunrin yìí; ẹ fi wọ́n sílẹ̀ o! Bí ète yìí tabi ohun tí wọn ń ṣe bá jẹ́ láti ọwọ́ eniyan, yóo parẹ́. Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ láti ọwọ́ Ọlọrun ni, ẹ kò lè pa wọ́n run, ẹ óo kàn máa bá Ọlọrun jagun ni!” Àwọn ìgbìmọ̀ rí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Wọ́n bá pe àwọn aposteli wọlé, wọ́n nà wọ́n, wọ́n kìlọ̀ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ fi orúkọ Jesu sọ̀rọ̀ mọ́. Wọ́n bá dá wọn sílẹ̀. Wọ́n jáde kúrò níwájú ìgbìmọ̀, wọ́n ń yọ̀ nítorí a kà wọ́n yẹ kún àwọn tí a fi àbùkù kan nítorí orúkọ Jesu. Lojoojumọ, ninu Tẹmpili ati láti ilé dé ilé, wọn kò dẹ́kun láti máa kọ́ eniyan ati láti máa waasu pé Jesu ni Mesaya. Nígbà tí ó yá, tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ń pọ̀ sí i, ìkùnsínú bẹ̀rẹ̀ láàrin àwọn tí ó ń sọ èdè Giriki ati àwọn tí ó ń sọ èdè Heberu, nítorí wọ́n ń fojú fo àwọn opó àwọn tí ń sọ èdè Giriki dá, nígbà tí wọ́n bá ń pín àwọn nǹkan ní ojoojumọ. Àwọn aposteli mejila bá pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu yòókù jọ, wọ́n ní, “Kò yẹ kí á fi iṣẹ́ iwaasu ọ̀rọ̀ Ọlọrun sílẹ̀, kí á máa ṣe ètò oúnjẹ. Nítorí náà, ẹ̀yin ará, ẹ wá ẹni meje láàrin yín, tí wọ́n ní orúkọ rere, tí wọ́n kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ ati ọgbọ́n, kí á yàn wọ́n láti mójútó ètò yìí. Àwa ní tiwa, a óo tẹra mọ́ adura gbígbà ati iṣẹ́ iwaasu ọ̀rọ̀ ìyìn rere.” Ọ̀rọ̀ yìí dára lójú gbogbo àwùjọ, wọ́n bá yan Stefanu. Stefanu yìí jẹ́ onigbagbọ tọkàntọkàn, tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Wọ́n yan Filipi náà ati Prokoru ati Nikanọ ati Timoni ati Pamena ati Nikolausi ará Antioku tí ó ti gba ẹ̀sìn àwọn Juu. Wọ́n kó wọn wá siwaju àwọn aposteli; wọ́n gbadura, wọ́n bá gbé ọwọ́ lé wọn lórí. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun wá ń gbilẹ̀. Iye àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu túbọ̀ ń pọ̀ sí i ní Jerusalẹmu. Pupọ ninu àwọn alufaa ni wọ́n sì di onigbagbọ. Stefanu ń ṣe iṣẹ́ ìyanu ati iṣẹ́ abàmì ńlá láàrin àwọn eniyan nítorí pé ẹ̀bùn ati agbára Ọlọrun pọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. Àwọn kan wá láti ilé ìpàdé kan tí à ń pè ní ti àwọn Olómìnira, ti àwọn ará Kurene ati àwọn ará Alẹkisandria; wọ́n tako Stefanu. Àwọn tí wọ́n wá láti Silisia ati láti Esia náà sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a jiyàn. Ṣugbọn wọn kò lè fèsì sí irú ọgbọ́n ati ẹ̀mí tí ó fi ń sọ̀rọ̀. Wọ́n bá rú àwọn eniyan nídìí, láti sọ pé, “A gbọ́ nígbà tí ó ń sọ ìsọkúsọ sí Mose ati sí Ọlọrun.” Wọ́n rú àwọn eniyan ati àwọn àgbààgbà ati àwọn amòfin nídìí, ni wọ́n bá mú un, wọ́n fà á lọ siwaju àwọn ìgbìmọ̀. Wọ́n wá àwọn ẹlẹ́rìí èké tí wọ́n sọ pé, “Ọkunrin yìí kò yé sọ̀rọ̀ lòdì sí Tẹmpili mímọ́ yìí ati sí òfin Mose. Nítorí a gbọ́ nígbà tí ó sọ pé Jesu ti Nasarẹti yóo wó ilé yìí, yóo yí àwọn àṣà tí Mose fún wa pada.” Gbogbo àwọn tí ó jókòó ní ìgbìmọ̀ tẹjú mọ́ ọn, wọ́n rí ojú rẹ̀ tí ó dàbí ojú angẹli. Olórí Alufaa bá bi í pé, “Ṣé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀ràn náà rí?” Stefanu bá tẹnu bọ̀rọ̀, ó ní, “Ẹ̀yin arakunrin ati baba mi, ẹ gbọ́ ohun tí mo ní sọ. Ọlọrun Ológo farahàn fún baba wa, Abrahamu, nígbà tí ó ṣì wà ní ilẹ̀ Mesopotamia, kí ó tó wá máa gbé ilẹ̀ Kenaani. Ó sọ fún un pé, ‘Jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ, láàrin àwọn ẹbí rẹ, kí o lọ sí ilẹ̀ tí èmi yóo fihàn ọ́.’ Ó bá jáde kúrò ní ilẹ̀ Kalidea láti máa gbé Kenaani. Nígbà tí baba rẹ̀ kú, ó kúrò níbẹ̀ láti wá máa gbé ilẹ̀ yìí, níbi tí ẹ̀ ń gbé nisinsinyii. Ní àkókò náà, Ọlọrun kò fún un ní ogún ninu ilẹ̀ náà, bí ó tilẹ̀ ṣe ẹsẹ̀ bàtà kan, kò ní níbẹ̀. Ṣugbọn Ọlọrun ṣe ìlérí láti fún òun ati ọmọ rẹ̀ tí yóo gbẹ̀yìn rẹ̀ ní ilẹ̀ náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní ọmọ ní àkókò náà. Ọlọrun sọ fún un pé, ‘Àwọn ọmọ rẹ yóo jẹ́ àlejò ní ilẹ̀ àjèjì. Àwọn eniyan ibẹ̀ yóo lò wọ́n bí ẹrú, wọn óo pọ́n wọn lójú fún irinwo (400) ọdún. Ṣugbọn orílẹ̀-èdè tí ó lò wọ́n bí ẹrú ni Èmi yóo dá lẹ́jọ́. Lẹ́yìn náà wọn yóo jáde kúrò ní ilẹ̀ àjèjì náà, wọn óo sì sìn mí ní ilẹ̀ yìí.’ Ọlọrun wá bá a dá majẹmu, ó fi ilà kíkọ ṣe àmì majẹmu náà. Nígbà tí ó bí Isaaki, ó kọ ọ́ nílà ní ọjọ́ kẹjọ. Isaaki bí Jakọbu. Jakọbu bí àwọn baba-ńlá wa mejila. “Àwọn baba-ńlá wa jowú Josẹfu, wọ́n tà á lẹ́rú sí ilẹ̀ Ijipti. Ṣugbọn Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀. Ọlọrun yọ ọ́ kúrò ninu gbogbo ìpọ́njú tí ó rí. Nígbà tí ó yọ siwaju Farao, ọba Ijipti, Ọlọrun fún un lọ́gbọ́n, ó sì jẹ́ kí ó rí ojú àánú ọba Ijipti. Farao bá fi jẹ gomina lórí gbogbo ilẹ̀ Ijipti ati lórí ààfin ọba. Nígbà tí ó yá, ìyàn mú ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti ati ní ilẹ̀ Kenaani. Eléyìí mú ìṣòro pupọ wá. Àwọn eniyan wa kò bá rí oúnjẹ jẹ. Nígbà tí Jakọbu gbọ́ pé oúnjẹ wà ní Ijipti, ó kọ́kọ́ rán àwọn baba wa lọ. Ní ẹẹkeji ni àwọn arakunrin rẹ̀ tó mọ ẹni tí Josẹfu jẹ́. A sì fi ìdílé Josẹfu han Farao. Josẹfu bá ranṣẹ láti pe Jakọbu baba rẹ̀ wá ati gbogbo àwọn ẹbí rẹ̀. Wọ́n jẹ́ eniyan marunlelaadọrin (75). Jakọbu bá lọ sí Ijipti. Níbẹ̀ ni ó kú sí, òun ati àwọn baba wa náà. Wọ́n gbé òkú wọn lọ sí Ṣekemu, wọ́n sin wọ́n sinu ibojì tí Abrahamu fowó rà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hamori ní Ṣekemu. “Nígbà tí ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò tí ìlérí tí Ọlọrun ṣe fún Abrahamu yóo ṣẹ, àwọn eniyan náà wá túbọ̀ ń pọ̀ níye ní Ijipti. Nígbà tó yá, ọba mìíràn tí kò mọ Josẹfu jẹ ní ilẹ̀ Ijipti. Ọba yìí bá fi ọgbọ́n àrékérekè bá orílẹ̀-èdè wa lò. Ó dá àwọn baba wa lóró, ó mú kí wọ́n máa sọ ọmọ nù, kí wọ́n baà lè kú. Ní àkókò yìí ni a bí Mose. Ó dára lọ́mọ pupọ. Àwọn òbí rẹ̀ tọ́ ọ fún oṣù mẹta ninu ilé baba rẹ̀ Nígbà tí wọ́n sọ ọ́ nù, ni ọmọ Farao, obinrin, bá tọ́ ọ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ti ara rẹ̀. Gbogbo ọgbọ́n àwọn ará Ijipti ni wọ́n fi kọ́ Mose. Ati ọ̀rọ̀ sísọ, ati iṣẹ́ ṣíṣe kò sí èyí tí kò mọ̀ ọ́n ṣe. “Nígbà tí Mose di ẹni ogoji ọdún, ó pinnu pé òun yóo lọ bẹ àwọn ará òun, àwọn ọmọ Israẹli, wò. Ó bá rí ọ̀kan ninu àwọn ará rẹ̀ tí ará Ijipti ń jẹ níyà. Ó bá lọ gbà á sílẹ̀. Ó gbẹ̀san ìyà tí wọ́n ti fi jẹ ẹ́, ó lu ará Ijipti náà pa. Ó rò pé yóo yé àwọn arakunrin òun pé Ọlọrun yóo ti ọwọ́ òun fún wọn ní òmìnira. Ṣugbọn kò yé wọn bẹ́ẹ̀. Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, ó yọ sí àwọn kan tí wọn ń jà. Ó bá ní kí òun parí ìjà fún wọn. Ó ní, ‘Ẹ̀yin ará, arakunrin ara yín ni ẹ̀ ń ṣe. Kí ló dé tí ẹ̀ ń lu ara yín?’ Ẹni tí ó jẹ̀bi tì í sẹ́yìn, ó ní, ‘Ta ni fi ọ́ ṣe olórí ati onídàájọ́ lórí wa? Ṣé o fẹ́ pa mí bí o ti ṣe pa ará Ijipti lánàá ni?’ Nígbà tí Mose gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó sálọ. Ó ń lọ gbé ilẹ̀ Midiani. Ó bí ọmọ meji níbẹ̀. “Lẹ́yìn ogoji ọdún, angẹli kán yọ sí i ninu ìgbẹ́ tí ń jóná ní aṣálẹ̀ lẹ́bàá òkè Sinai. Nígbà tí Mose rí ìran náà, ẹnu yà á. Nígbà tí ó súnmọ́ ọn pé kí òun wò ó fínnífínní, ó gbọ́ ohùn Oluwa tí ó sọ pé, ‘Èmi ni Ọlọrun àwọn baba rẹ, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati ti Jakọbu.’ Mose bá bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n. Kò tó ẹni tí í wò ó. Oluwa tún sọ fún un pé, ‘Bọ́ sálúbàtà tí ó wà lẹ́sẹ̀ rẹ, nítorí ilẹ̀ mímọ́ ni ibi tí o dúró sí. Mo ti rí gbogbo ìrora tí àwọn eniyan mi ń jẹ ní Ijipti. Mo ti gbọ́ ìkérora wọn, mo sì ṣetán láti yọ wọ́n. Ó yá nisinsinyii. N óo rán ọ lọ sí Ijipti.’ “Mose yìí kan náà, tí wọ́n kọ̀, tí wọ́n sọ fún pé, ‘Ta ni ó fi ọ́ ṣe olórí ati onídàájọ́?’ Òun ni Ọlọrun rán angẹli sí, tí ó farahàn án ninu ìgbẹ́ tí ń jó, láti jẹ́ olórí ati olùdáǹdè. Mose yìí ni aṣaaju wọn, tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ati iṣẹ́ abàmì ní ilẹ̀ Ijipti ní Òkun Pupa ati ní ilẹ̀ aṣálẹ̀ fún ogoji ọdún. Mose yìí ni ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ọlọrun yóo gbé wolii kan bí èmi dìde fun yín láàrin àwọn arakunrin yín.’ Mose náà ni ó bá angẹli sọ̀rọ̀ ní òkè Sinai nígbà tí wọ́n wà ninu àwùjọ ní aṣálẹ̀, tí ó tún bá àwọn baba wa sọ̀rọ̀. Òun ni ó gba ọ̀rọ̀ ìyè láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun tí ó fi fún wa. “Ṣugbọn àwọn baba wa kò fẹ́ gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́. Wọ́n tì í kúrò lọ́dọ̀ wọn; ọkàn wọn tún pada sí Ijipti. Wọ́n sọ fún Aaroni pé, ‘Ṣe oriṣa fún wa kí á rí ohun máa bọ, kí ó máa tọ́ wa sí ọ̀nà. A kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Mose tí ó kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti.’ Wọ́n bá ṣe ère ọmọ mààlúù kan ní àkókò náà, wọ́n rúbọ sí i. Wọ́n bá ń ṣe àríyá lórí ohun tí wọ́n fi ọwọ́ wọn ṣe. Ọlọrun bá pada lẹ́yìn wọn, ó fi wọ́n sílẹ̀ láti máa sin ìràwọ̀ ojú ọ̀run, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ninu ìwé àwọn wolii pé, ‘Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ǹjẹ́ ẹ mú ẹran wá fi rúbọ sí mi fún ogoji ọdún ní aṣálẹ̀? Ṣebí àtíbàbà Moleki ni ẹ gbé rù, ati ìràwọ̀ Refani oriṣa yín, àwọn ère tí ẹ ṣe láti máa foríbalẹ̀ fún? N óo le yín lọ sí ìgbèkùn, ẹ óo kọjá Babiloni.’ “Àwọn baba wa ní àgọ́ ẹ̀rí kan ní aṣálẹ̀. Ọlọrun bá Mose sọ̀rọ̀, ó sì pàṣẹ fún un pé kí ó ṣe àgọ́ yìí gẹ́gẹ́ bí àwòrán tí òun ti fihàn án tẹ́lẹ̀. Àwọn baba wa tí wọ́n tẹ̀lé Joṣua gba ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí Ọlọrun lé kúrò níwájú wọn, lẹ́yìn náà wọ́n gbé àgọ́ náà wá. Àgọ́ yìí sì wà pẹlu wa títí di àkókò Dafidi. Dafidi bá ojurere Ọlọrun pàdé; ó wá bèèrè pé kí Ọlọrun jẹ́ kí òun kọ́ ilé fún òun, Ọlọrun Jakọbu. Ṣugbọn Solomoni ni ó kọ́ ilé fún un. “Bẹ́ẹ̀ ni Ọba tí ó ga jùlọ kì í gbé ilé tí a fi ọwọ́ kọ́. Gẹ́gẹ́ bí wolii nì ti sọ: ‘Ọ̀run ni ìtẹ́ mi, ayé ni tìmùtìmù ìtìsẹ̀ mi. Irú ilé wo ni ẹ̀ báà kọ́ fún mi? Bẹ́ẹ̀ ni Oluwa wí. Níbo ni ẹ̀ báà palẹ̀ mọ́ fún mi pé kí n ti máa sinmi? Ṣebí èmi ni mo fọwọ́ mi ṣe gbogbo nǹkan wọnyi?’ “Ẹ̀yin olóríkunkun, ọlọ́kàn líle, elétí dídi wọnyi! Nígbà gbogbo ni ẹ̀ ń tako Ẹ̀mí Mímọ́. Bí àwọn baba yín ti rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà rí. Èwo ninu àwọn wolii ni àwọn Baba yín kò ṣe inúnibíni sí? Wọ́n pa àwọn tí wọ́n sọtẹ́lẹ̀ pé Ẹni olódodo yóo dé. Ní àkókò yìí ẹ wá dìtẹ̀ sí i, ẹ ṣe ikú pa á. Ẹ̀yin yìí ni ẹ gba òfin Ọlọrun láti ọwọ́ àwọn angẹli, ṣugbọn ẹ kò pa òfin náà mọ́.” Nígbà tí wọ́n gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ yìí, ó gún wọn lọ́kàn. Wọ́n bá pòṣé sí i. Ṣugbọn Ẹ̀mí Mímọ́ gbé Stefanu, ó tẹ ojú mọ́ òkè ọ̀run, ó rí ògo Ọlọrun, ó tún rí Jesu tí ó dúró lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọrun. Ó bá dáhùn pé, “Ẹ wò ó, mo rí ojú ọ̀run tí ó pínyà. Mo wá rí Ọmọ-Eniyan tí ó dúró lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọrun.” Ni wọ́n bá kígbe, wọ́n fi ọwọ́ di etí, gbogbo wọ́n rọ́ lù ú; wọ́n fà á jáde lọ sí ẹ̀yìn ìlú, wọ́n bá ń sọ ọ́ ní òkúta. Àwọn ẹlẹ́rìí fi ẹ̀wù wọn lélẹ̀ níwájú ọdọmọkunrin kan tí à ń pè ní Saulu. Bí wọ́n ti ń sọ òkúta lu Stefanu, ó ké pe Jesu Oluwa, ó ní, “Oluwa Jesu, gba ẹ̀mí mi.” Ni ó bá kúnlẹ̀, ó kígbe, ó ní, “Oluwa, má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ yìí sí wọn lọ́rùn.” Nígbà tí ó sọ báyìí tán, ó kú. Saulu bá wọn lọ́wọ́ sí ikú rẹ̀. Láti ọjọ́ náà ni inúnibíni ńlá ti bẹ̀rẹ̀ sí ìjọ tí ó wà ní Jerusalẹmu. Gbogbo àwọn onigbagbọ bá túká lọ sí gbogbo agbègbè Judia ati Samaria. Àwọn aposteli nìkan ni kò kúrò ní ìlú. Àwọn olùfọkànsìn sin òkú Stefanu, wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ pupọ lórí rẹ̀. Ṣugbọn Saulu bẹ̀rẹ̀ sí da ìjọ rú. Ó ń wọ ojúlé kiri, ó ń fa tọkunrin tobinrin jáde, lọ sẹ́wọ̀n. Àwọn tí wọ́n túká bá ń lọ káàkiri, wọ́n ń waasu ọ̀rọ̀ náà. Filipi lọ sí ìlú Samaria kan, ó waasu fún wọn nípa Kristi. Àwọn eniyan ṣù bo Filipi kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, wọ́n sì ń rí iṣẹ́ abàmì tí ó ń ṣe. Nítorí àwọn ẹ̀mí burúkú ń lọgun bí wọ́n ti ń jáde kúrò ninu ọpọlọpọ eniyan. Bẹ́ẹ̀ ni a mú ọpọlọpọ àwọn arọ ati àwọn tí wọ́n ní àbùkù ara lára dá. Inú àwọn eniyan dùn pupọ ní ìlú náà. Ọkunrin kán wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Simoni, tí ó ti máa ń pidán ní ìlú náà. Èyí jẹ́ ìyanu fún àwọn ará Samaria, wọ́n ní ẹni ńlá ni ọkunrin náà. Gbogbo eniyan ló kà á kún; ati àwọn eniyan yẹpẹrẹ ati àwọn eniyan pataki wọn. Wọ́n ní, “Eléyìí ní agbára Ọlọrun tí à ń pè ní ‘Agbára ńlá.’ ” Tẹ́lẹ̀ rí òun ni àwọn eniyan kà kún, tí idán tí ó ń pa ń yà wọ́n lẹ́nu. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n gba ìyìn rere tí Filipi waasu nípa ìjọba Ọlọrun ati orúkọ Jesu Kristi gbọ́, tọkunrin tobinrin wọn ṣe ìrìbọmi. Simoni náà gbàgbọ́, ó ṣe ìrìbọmi, ni ó bá fara mọ́ Filipi. Nígbà tí ó rí iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu ńlá tí ó ń ṣe, ẹnu yà á. Àwọn aposteli tí ó wà ní Jerusalẹmu gbọ́ bí àwọn ará Samaria ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Wọ́n bá rán Peteru ati Johanu sí wọn. Nígbà tí wọ́n dé, wọ́n gbadura fún wọn kí wọ́n lè gba Ẹ̀mí Mímọ́, nítorí Ẹ̀mí Mímọ́ kò ì tíì bà lé ẹnikẹ́ni ninu wọn. Ìrìbọmi ní orúkọ Oluwa Jesu nìkan ni wọ́n ṣe. Lẹ́yìn tí Peteru ati Johanu ti gbé ọwọ́ lé wọn, wọ́n bá gba Ẹ̀mí Mímọ́. Nígbà tí Simoni rí i pé ọwọ́ tí àwọn aposteli gbé lé wọn ni ó mú kí wọ́n rí Ẹ̀mí gbà, ó fi owó lọ̀ wọ́n. Ó ní, “Ẹ fún mi ní irú àṣẹ yìí kí ẹni tí mo bá gbé ọwọ́ lé, lè gba Ẹ̀mí Mímọ́.” Ṣugbọn Peteru sọ fún un pé, “Ìwọ ati owó rẹ yóo ṣègbé! O rò pé o lè fi owó ra ẹ̀bùn Ọlọrun. O kò ní ipa tabi ìpín ninu ọ̀rọ̀ yìí, nítorí ọkàn rẹ kò tọ́ níwájú Ọlọrun. Nítorí náà, ronupiwada kúrò ninu ohun burúkú yìí, kí o tún bẹ Oluwa kí ó dárí èrò ọkàn rẹ yìí jì ọ́. Nítorí mo wòye pé ẹ̀tanú ti gbà ọ́ lọ́kàn, àtipé aiṣododo ti dè ọ́ lẹ́wọ̀n.” Simoni dá Peteru lóhùn pé, “Ẹ gbadura sí Oluwa fún mi kí ohunkohun tí ẹ wí má ṣẹlẹ̀ sí mi.” Lẹ́yìn tí Peteru ati Johanu ti jẹ́rìí tí wọ́n ti sọ ọ̀rọ̀ Oluwa tán, wọ́n pada sí Jerusalẹmu. Wọ́n ń waasu ìyìn rere ní ọpọlọpọ àwọn abúlé ilẹ̀ Samaria bí wọ́n ti ń pada lọ. Angẹli Oluwa sọ fún Filipi pé, “Dìde kí o lọ sí apá gúsù, ní ọ̀nà tí ó lọ láti Jerusalẹmu sí Gasa.” (Aṣálẹ̀ ni ọ̀nà yìí gbà lọ.) Ni Filipi bá dìde lọ. Ó bá rí ọkunrin ará Etiopia kan. Ó jẹ́ ìwẹ̀fà onípò gíga kan lábẹ́ Kandake, ọbabinrin Etiopia. Òun ni akápò ìjọba. Ó ti lọ ṣe ìsìn ní Jerusalẹmu, ó wá ń pada lọ sílé. Ó jókòó ninu ọkọ̀ ẹlẹ́ṣin rẹ̀, ó ń ka ìwé wolii Aisaya. Ẹ̀mí sọ fún Filipi pé, “Lọ síbi ọkọ nnì kí o súnmọ́ ọn.” Nígbà tí Filipi sáré, tí ó súnmọ́ ọn, ó gbọ́ tí ó ń ka ìwé wolii Aisaya. Ó bi í pé, “Ǹjẹ́ ohun tí ò ń kà yé ọ?” Ó dáhùn pé, “Ó ṣe lè yé mi láìjẹ́ pé ẹnìkan bá ṣe àlàyé rẹ̀ fún mi?” Ó bá bẹ Filipi pé kí ó gòkè wọ inú ọkọ̀, kí ó jókòó ti òun. Apá ibi tí ó ń kà nìyí: “Bí aguntan tí a mú lọ sí ilé ìpẹran, tí à ń fà níwájú àwọn tí ń rẹ́ irun rẹ̀, kò fọhùn, bẹ́ẹ̀ ni kò ya ẹnu rẹ̀. A rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀. A kò ṣe ẹ̀tọ́ nípa ọ̀ràn rẹ̀. Ẹnikẹ́ni kò ní lè sọ nípa ìran rẹ̀. Nítorí a pa á run kúrò lórí ilẹ̀ alààyè.” Ìwẹ̀fà náà sọ fún Filipi pé, “Mo bẹ̀ ọ́, ọ̀rọ̀ ta ni wolii Ọlọrun yìí ń sọ, ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ ni tabi ọ̀rọ̀ ẹlòmíràn?” Filipi bá tẹnu bọ ọ̀rọ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ láti ibi àkọsílẹ̀ yìí, ó waasu ìyìn rere Jesu fún un. Bí wọn tí ń lọ lọ́nà, wọ́n dé odò kan. Ìwẹ̀fà náà sọ pé, “Wo omi. Kí ló dé tí o ò fi kúkú rì mí bọmi?” [ Filipi sọ fún un pé, “Bí o bá gbàgbọ́ tọkàntọkàn, ẹ̀tọ́ ni.” Ó dáhùn pé, “Mo gbàgbọ́ pé Ọmọ Ọlọrun ni Jesu Kristi.”] Ìwẹ̀fà náà bá pàṣẹ pé kí ọkọ̀ dúró. Òun ati Filipi bá sọ̀kalẹ̀, wọ́n lọ sinu odò, Filipi bá rì í bọmi. Nígbà tí wọ́n jáde kúrò ninu odò. Ẹ̀mí Oluwa gbé Filipi lọ, ìwẹ̀fà náà kò sì rí i mọ́. Ó bá ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ pẹlu ayọ̀. Ní Asotu ni a tún ti rí Filipi. Ó ń waasu ní gbogbo àwọn ìlú tí ó gbà kọjá títí ó fi dé Kesaria. Ní gbogbo àkókò yìí, Saulu ń fi ikú dẹ́rùba àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Oluwa. Ó lọ sọ́dọ̀ Olórí Alufaa, ó gba ìwé lọ́dọ̀ rẹ̀ láti lọ sí àwọn ilé ìpàdé tí ó wà ní Damasku. Ìwé yìí fún un ní àṣẹ pé bí ó bá rí àwọn tí ń tẹ̀lé ọ̀nà ẹ̀sìn yìí, ìbáà ṣe ọkunrin ìbáà ṣe obinrin, kí ó dè wọ́n, kí ó sì fà wọ́n wá sí Jerusalẹmu. Bí ó ti ń lọ lọ́nà, tí ó súnmọ́ Damasku, iná kan mọ́lẹ̀ yí i ká lójijì; ó bá ṣubú lulẹ̀. Ó wá gbọ́ ohùn ẹnìkan tí ó bi í pé, “Saulu! Saulu! Kí ló dé tí o fi ń ṣe inúnibíni sí mi?” Saulu bèèrè pé, “Ta ni ọ́, Oluwa?” Ẹni náà bá dáhùn pé, “Èmi ni Jesu, ẹni tí ò ń ṣe inúnibíni sí. Dìde nisinsinyii, kí o wọ inú ìlú lọ. A óo sọ ohun tí o níláti ṣe fún ọ.” Àwọn ọkunrin tí ó ń bá a rìn dúró. Wọn kò sọ ohunkohun. Wọ́n ń gbọ́ ohùn eniyan, ṣugbọn wọn kò rí ẹnìkankan. Saulu bá dìde nílẹ̀, ó la ojú sílẹ̀ ṣugbọn kò ríran. Wọ́n bá fà á lọ́wọ́ lọ sí Damasku. Fún ọjọ́ mẹta, kò ríran, kò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò mu. Ọmọ-ẹ̀yìn Jesu kan wà ní Damasku tí ń jẹ́ Anania. Oluwa pè é ní ojú ìran, ó ní, “Anania!” Anania bá dáhùn pé, “Èmi nìyí, Oluwa.” Oluwa bá sọ fún un pé, “Dìde. Lọ sí títì tí à ń pè ní ‘Títì títọ́,’ ní ilé Judasi kí o bèèrè ẹni tí ó ń jẹ́ Saulu, ará Tasu. O óo bá a ní ibi tí ó gbé ń gbadura. Ní ojú ìran, ó rí ọkunrin kan tí ń jẹ́ Anania, tí ó wọlé tọ̀ ọ́ lọ, tí ó fi ọwọ́ bà á lójú kí ó lè tún ríran.” Anania dáhùn pé, “Oluwa, mo ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ọkunrin yìí lẹ́nu ọpọlọpọ eniyan: oríṣìíríṣìí ibi ni ó ti ṣe sí àwọn eniyan mímọ́ rẹ ní Jerusalẹmu. Wíwá tí ó tún wá síhìn-ín, ó wá pẹlu àṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa láti de gbogbo àwọn tí ó ń pe orúkọ rẹ ni.” Oluwa sọ fún un pé, “Lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí mo ti yàn án láti mú orúkọ mi lọ siwaju àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ati àwọn ọba wọn ati àwọn ọmọ Israẹli. N óo fi oríṣìíríṣìí ìyà tí ó níláti jẹ nítorí orúkọ mi hàn án.” Anania bá lọ, ó wọ inú ilé náà, ó fi ọwọ́ kan Saulu. Ó ní, “Saulu arakunrin mi, Oluwa ni ó rán mi sí ọ. Jesu tí ó farahàn ọ́ ní ojú ọ̀nà tí o gbà wá, ni ó rán mi wá, kí o lè tún ríran, kí o sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́.” Lẹsẹkẹsẹ nǹkankan bọ́ sílẹ̀ lójú rẹ̀ bí ìpẹ́pẹ́, ó sì tún ríran. Ó dìde, ó bá gba ìrìbọmi. Ó bá jẹun, ara rẹ̀ bá tún mókun. Ó wà pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu tí ó wà ní Damasku fún ọjọ́ díẹ̀. Láì jáfara ó bẹ̀rẹ̀ sí waasu ninu ilé ìpàdé àwọn Juu pé Jesu ni Ọmọ Ọlọrun. Ẹnu ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Wọ́n ní “Ará ibí yìí kọ́ ni ó ń pa àwọn tí ó ń pe orúkọ yìí ní Jerusalẹmu, tí ó tún wá síhìn-ín láti fi ẹ̀wọ̀n dè wọ́n, tí ó fẹ́ fà wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí alufaa?” Ṣugbọn ńṣe ni Saulu túbọ̀ ń lágbára sí i. Àwọn Juu tí ó ń gbé Damasku kò mọ ohun tí wọ́n le wí mọ́, nítorí ó fi ẹ̀rí hàn pé Jesu ni Mesaya. Bí ọjọ́ tí ń gorí ọjọ́ àwọn Juu gbèrò pọ̀ bí wọn yóo ti ṣe pa á. Ṣugbọn Saulu gbọ́ nípa ète wọn. Wọ́n ń ṣọ́ àwọn ẹnu odi ìlú tọ̀sán-tòru kí wọ́n baà lè pa á. Ṣugbọn ní alẹ́ ọjọ́ kan, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbé e sinu apẹ̀rẹ̀, wọ́n sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti orí odi ìlú. Nígbà tí Saulu dé Jerusalẹmu, ó fẹ́ darapọ̀ mọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu. Ṣugbọn ẹ̀rù rẹ̀ ń bà wọ́n; wọn kò gbàgbọ́ pé ó ti di ọmọ-ẹ̀yìn Jesu. Ṣugbọn Banaba mú un lọ sọ́dọ̀ àwọn aposteli, ó ròyìn fún wọn bí ó ti rí Oluwa lọ́nà, bí Oluwa ti bá a sọ̀rọ̀, ati bí ó ti fi ìgboyà waasu lórúkọ Jesu ní Damasku. Ó bá ń bá wọn gbé ní Jerusalẹmu, ó ń wọlé, ó ń jáde, ó ń fi ìgboyà waasu lórúkọ Oluwa, ó ń bá àwọn Juu tí ó ń sọ èdè Giriki jiyàn. Ṣugbọn wọ́n gbèrò láti pa á. Nígbà tí àwọn onigbagbọ mọ̀, wọ́n sìn ín lọ sí Kesaria, wọ́n fi ranṣẹ sí Tasu. Gbogbo ìjọ ní Judia, ati Galili, ati Samaria wà ní alaafia, wọ́n sì fìdí múlẹ̀. Wọ́n ń gbé ìgbé-ayé wọn pẹlu ìbẹ̀rù Oluwa, wọ́n sì ń pọ̀ sí i nípa ìrànlọ́wọ́ Ẹ̀mí Mímọ́. Bí Peteru tí ń lọ káàkiri láti ibìkan dé ibi keji, ó dé ọ̀dọ̀ àwọn eniyan Ọlọrun tí wọn ń gbé ìlú Lida. Ó rí ọkunrin kan níbẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Iniasi tí ó ti wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn fún ọdún mẹjọ; kò lè dá ara gbé nílẹ̀. Peteru bá sọ fún un pé, “Iniasi, Jesu Kristi wò ọ́ sàn. Dìde, kà ẹní rẹ.” Lẹsẹkẹsẹ, ó bá dìde. Gbogbo àwọn tí ó ń gbé Lida ati Ṣaroni rí i, wọ́n bá yipada, wọ́n di onigbagbọ. Ọmọ-ẹ̀yìn kan wà ní Jọpa, tí ó jẹ́ obinrin, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tabita, tabi Dọkasi ní èdè Giriki. (Ìtumọ̀ rẹ̀ ni èkùlù.) Obinrin yìí jẹ́ ẹnìkan tíí máa ṣe ọpọlọpọ iṣẹ́ rere, ó sì láàánú pupọ. Ní àkókò yìí ó wá ṣàìsàn, ó sì kú. Wọ́n bá wẹ̀ ẹ́, wọ́n tẹ́ ẹ sí yàrá lókè ní ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì kan. Lida kò jìnnà sí Jọpa, nítorí náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ní Jọpa ti gbọ́ pé Peteru wà ní Lida. Wọ́n bá rán ọkunrin meji lọ sibẹ, kí wọ́n lọ bẹ̀ ẹ́ pé kí ó má jáfara kí ó yára wá sọ́dọ̀ wọn. Peteru bá gbéra, ó tẹ̀lé wọn. Nígbà tí ó dé Jọpa, ó lọ sí iyàrá lókè. Gbogbo àwọn opó bá yí i ká, wọ́n ń sunkún, wọ́n ń fi àwọn ẹ̀wù ati aṣọ tí Dọkasi máa ń rán fún wọn nígbà tí ó wà láàyè han Peteru. Peteru bá ti gbogbo wọn jáde, ó kúnlẹ̀, ó gbadura. Ó bá kọjú sí òkú náà, ó ní, “Tabita, dìde.” Ni Tabita bá lajú, ó rí Peteru, ó bá dìde jókòó. Peteru bá fà á lọ́wọ́ dìde. Ó pe àwọn eniyan Ọlọrun ati àwọn opó, ó bá fa Dọkasi lé wọn lọ́wọ́ láàyè. Ìròyìn yìí tàn ká gbogbo Jọpa, ọpọlọpọ sì gba Oluwa gbọ́. Peteru dúró fún ọjọ́ pupọ ní Jọpa, ní ọ̀dọ̀ Simoni, tí ń ṣe òwò awọ. Ọkunrin kan wà ní Kesaria tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kọniliu. Ó jẹ́ balogun ọ̀rún ti ẹgbẹ́ tí à ń pè ní Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Itali. Olùfọkànsìn ni. Òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀ sì bẹ̀rù Ọlọrun. A máa ṣàánú àwọn eniyan lọpọlọpọ, a sì máa gbadura sí Ọlọrun nígbà gbogbo. Ní ọjọ́ kan, ní nǹkan agogo mẹta ọ̀sán, ó rí ìran kan. Angẹli Ọlọrun wọlé tọ̀ ọ́ wá, ó ní, “Kọniliu!” Kọniliu bá tẹjú mọ́ ọn. Ẹ̀rù bà á, ó ní, “Kí ló dé, alàgbà?” Angẹli yìí bá sọ fún un pé, “Adura rẹ ti gbà; iṣẹ́ àánú rẹ ti gòkè lọ siwaju Ọlọrun. Ọlọrun sì ti ranti rẹ. Nisinsinyii wá rán àwọn kan lọ sí Jọpa, kí wọn lọ pe ẹnìkan tí ń jẹ́ Simoni, tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Peteru, kí ó wá. Ó dé sílé ẹnìkan tí ń jẹ́ Simoni, tí ń ṣe òwò awọ, tí ilé rẹ̀ wà létí òkun.” Bí angẹli tí ó ń bá a sọ̀rọ̀ ti lọ tán, ó pe meji ninu àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati ọmọ-ogun olùfọkànsìn kan, ọ̀kan ninu àwọn tí ó máa ń dúró tì í tímọ́tímọ́. Ó ròyìn ohun gbogbo fún wọn, ó bá rán wọn lọ sí Jọpa. Ní ọjọ́ keji, bí wọ́n ti ń bá ìrìn àjò wọn lọ, tí wọ́n súnmọ́ Jọpa, Peteru gun òkè ilé lọ láti gbadura ní nǹkan agogo mejila ọ̀sán. Ebi dé sí i, ó wá ń wá nǹkan tí yóo jẹ. Bí wọ́n ti ń tọ́jú oúnjẹ lọ́wọ́, Peteru bá rí ìran kan. Ó rí ọ̀run tí ó pínyà, tí nǹkankan bí aṣọ tí ó fẹ̀, tí ó ní igun mẹrin, ń bọ̀ wálẹ̀, títí ó fi dé ilẹ̀. Gbogbo ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹrin ati oríṣìíríṣìí ẹranko tí ó ń fi àyà fà, ati ẹyẹ ojú ọ̀run ni ó wà ninu rẹ̀. Ó wá gbọ́ ohùn ẹnìkan tí ó ń bá a sọ̀rọ̀, ó ní, “Peteru dìde, pa ẹran kí o jẹ ẹ́!” Ṣugbọn Peteru dáhùn pé, “Èèwọ̀ Oluwa! N kò jẹ ẹrankẹ́ran tabi ẹran àìmọ́ kan rí.” Ohùn náà tún dún létí rẹ̀ lẹẹkeji pé, “Ohun tí Ọlọrun bá ti sọ di mímọ́, o kò gbọdọ̀ pè é ní ohun àìmọ́!” Èyí ṣẹlẹ̀ lẹẹmẹta. Lẹsẹkẹsẹ a tún gbé aṣọ náà lọ sókè ọ̀run. Ìran tí Peteru rí yìí rú u lójú. Bí ó ti ń rò ó pé kí ni ìtumọ̀ ohun tí òun rí yìí, àwọn tí Kọniliu rán sí i ti wádìí ibi tí ilé Simoni wà, wọ́n ti dé ẹnu ọ̀nà. Wọ́n ké “Àgò!” wọ́n sì ń bèèrè bí Simoni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Peteru bá dé sibẹ. Bí Peteru ti ń ronú lórí ìran yìí, Ẹ̀mí sọ fún un pé, “Àwọn ọkunrin mẹta ń wá ọ. Dìde, lọ sí ìsàlẹ̀, kí o bá wọn lọ láì kọminú nítorí èmi ni mo rán wọn.” Nígbà tí Peteru dé ìsàlẹ̀, ó wí fún àwọn ọkunrin náà pé, “Èmi tí ẹ̀ ń wá nìyí, kí ni ẹ̀ ń fẹ́ o?” Wọ́n bá dáhùn pé, “Kọniliu ọ̀gágun ni ó rán wa wá; eniyan rere ni, ó sì bẹ̀rù Ọlọrun tóbẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn ọmọ Juu fi lè jẹ́rìí sí i. Angẹli Oluwa ni ó sọ fún un pé kí ó ranṣẹ pè ọ́ wá sí ilé rẹ̀, kí ó lè gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ.” Ni Peteru bá pè wọ́n wọlé, ó gbà wọ́n lálejò. Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, ó dìde, ó bá wọn lọ. Àwọn kan ninu àwọn ọmọ ìjọ ní Jọpa sì tẹ̀lé wọn. Ní ọjọ́ keji tí wọ́n gbéra ní Jọpa ni wọ́n dé Kesaria. Kọniliu ti ń retí wọn. Ó ti pe àwọn ẹbí ati àwọn tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ jọ. Bí Peteru ti fẹ́ wọlé, Kọniliu lọ pàdé rẹ̀. Ó kúnlẹ̀, ó sì foríbalẹ̀. Ṣugbọn Peteru fà á dìde, ó ní, “Dìde! Eniyan ni èmi náà.” Bí ó ti ń bá a sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó bá a wọlé. Ó rí ọ̀pọ̀ eniyan tí ó ti péjọ. Ó sọ fún wọn pé, “Ó ye yín pé ó lòdì sí òfin wa pé kí ẹni tíí ṣe Juu kí ó ní nǹkan í ṣe pẹlu ẹni tí ó jẹ́ ẹ̀yà mìíràn, tabi kí ó lọ bẹ̀ ẹ́ wò ninu ilé rẹ̀. Ṣugbọn Ọlọrun ti fihàn mí pé n kò gbọdọ̀ pe ẹnikẹ́ni ni eniyan lásán tabi aláìmọ́. Ìdí tí mo ṣe wá láì kọminú nìyí nígbà tí o ranṣẹ sí mi. Mo wá fẹ́ mọ ìdí rẹ̀ tí o fi ranṣẹ sí mi.” Kọniliu dáhùn pé, “Ní ijẹrin, ní déédé àkókò yìí, mo ń gbadura ninu ilé mi ní agogo mẹta ọ̀sán. Ọkunrin kan bá yọ sí mi, ó wọ aṣọ dídán. Ó ní, ‘Kọniliu, Ọlọrun ti gbọ́ adura rẹ, ó sì ti ranti iṣẹ́ àánú rẹ. Nítorí náà, ranṣẹ lọ sí Jọpa, kí o lọ pe Simoni tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Peteru wá. Ó dé sílé Simoni tí ń ṣe òwò awọ, létí òkun.’ Lẹsẹkẹsẹ ni mo bá ranṣẹ sí ọ. O ṣeun tí o wá. Nisinsinyii gbogbo wa wà níwájú Ọlọrun láti gbọ́ ohun gbogbo tí Oluwa ti pa láṣẹ fún ọ láti sọ.” Peteru bá tẹnu bọ̀rọ̀. Ó ní, “Ó wá yé mi gan-an pé Ọlọrun kì í ṣe ojuṣaaju. Ẹnikẹ́ni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣe rere ni yóo fà mọ́ra láì bèèrè orílẹ̀-èdè tí ó jẹ́. Ẹ mọ iṣẹ́ tí ó rán sí àwọn ọmọ Israẹli, ọ̀rọ̀ ìyìn rere alaafia nípasẹ̀ Jesu Kristi, ẹni tíí ṣe Oluwa gbogbo eniyan. Ẹ mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní gbogbo Judia. Ó bẹ̀rẹ̀ láti Galili lẹ́yìn ìrìbọmi tí Johanu ń sọ pé kí àwọn eniyan ṣe. Ẹ mọ̀ nípa Jesu ará Nasarẹti, bí Ọlọrun ti ṣe yàn án, tí ó fún un ní Ẹ̀mí Mímọ́ ati agbára; bí ó ti ṣe ń lọ káàkiri tí ó ń ṣe rere, tí ó ń wo gbogbo àwọn tí Satani ti ń dá lóró sàn, nítorí Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀. Àwa yìí ni ẹlẹ́rìí gbogbo ohun tí ó ṣe ní ilẹ̀ àwọn Juu ati ní Jerusalẹmu. Wọ́n kan ọkunrin yìí mọ́ agbelebu. Ṣugbọn Ọlọrun jí i dìde ní ọjọ́ kẹta, ó sì jẹ́ kí eniyan rí i. Kì í ṣe gbogbo eniyan ni ó rí i bíkòṣe àwọn ẹlẹ́rìí tí Ọlọrun ti yàn tẹ́lẹ̀, àwa tí a bá a jẹ, tí a bá a mu lẹ́yìn tí ó jinde kúrò ninu òkú. Ó wá pàṣẹ fún wa láti waasu fún àwọn eniyan, kí á fi yé wọn pé Jesu yìí ni ẹni tí Ọlọrun ti yàn láti jẹ́ onídàájọ́ àwọn tí ó ti kú ati àwọn tí ó wà láàyè. Òun ni gbogbo àwọn wolii ń jẹ́rìí sí, tí wọ́n sọ pé gbogbo ẹni tí ó bá gbà á gbọ́ yóo ní ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ní orúkọ rẹ̀.” Bí Peteru ti ń sọ̀rọ̀ báyìí lọ́wọ́, kò tíì dákẹ́ ọ̀rọ̀ tí ń sọ, bẹ́ẹ̀ ni Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé gbogbo àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. Ẹnu ya àwọn onigbagbọ tí wọ́n jẹ́ Juu tí wọ́n bá Peteru wá nítorí àwọn tí kì í ṣe Juu rí ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ gbà lọ́fẹ̀ẹ́ ati lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Wọ́n gbọ́ tí wọn ń fi oríṣìíríṣìí èdè sọ̀rọ̀, tí wọn ń yin Ọlọrun fún iṣẹ́ ńlá rẹ̀. Peteru bá bèèrè pé, “Ta ló rí ohun ìdíwọ́ kan, ninu pé kí á ṣe ìrìbọmi fún àwọn wọnyi, tí wọ́n gba Ẹ̀mí Mímọ́ bí àwa náà ti gbà á?” Lẹ́yìn náà, ó pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe ìrìbọmi ní orúkọ Jesu Kristi. Wọ́n bá bẹ̀ ẹ́ kí ó dúró lọ́dọ̀ wọn fún ọjọ́ díẹ̀. Àwọn aposteli ati àwọn onigbagbọ yòókù tí ó wà ní Judia gbọ́ pé àwọn tí kì í ṣe Juu náà ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Nígbà tí Peteru pada dé Jerusalẹmu, àwọn onigbagbọ tí ó jẹ́ Juu dá àríyànjiyàn sílẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà. Wọ́n ní, “O wọlé tọ àwọn eniyan tí kò kọlà lọ, o sì bá wọn jẹun!” Peteru bá tẹnu bọ̀rọ̀, ó ro gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún wọn lẹ́sẹẹsẹ. Ó ní, “Ìlú Jọpa ni mo wà tí mò ń gbadura, ni mo bá rí ìran kan. Nǹkankan tí ó dàbí aṣọ tí ó fẹ̀, tí wọ́n so ní igun mẹrin ń sọ̀kalẹ̀ bọ̀ láti ọ̀run títí ó fi dé ọ̀dọ̀ mi. Mo tẹjú mọ́ ọn láti wo ohun tí ó wà ninu rẹ̀. Mo bá rí àwọn ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹrin ati àwọn ẹranko ìgbẹ́ ati àwọn ẹranko tí ń fi àyà wọ́, ati àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run. Mo wá gbọ́ ohùn ẹnìkan tí ó sọ fún mi pé, ‘Peteru, dìde, pa àwọn ẹran tí o bá fẹ́, kí o sì jẹ.’ Ṣugbọn mo ní, ‘Èèwọ̀, Oluwa! N kò jẹ ẹrankẹ́ran tabi ẹran àìmọ́ kan rí.’ Lẹẹkeji ohùn náà tún wá láti ọ̀run. Ó ní, ‘Ohunkohun tí Ọlọrun bá ti sọ di mímọ́, ìwọ kò gbọdọ̀ pè é ní aláìmọ́ mọ́.’ Ẹẹmẹta ni ó ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, ni nǹkankan bá tún fa gbogbo wọn pada sí ọ̀run. Lákòókò náà gan-an ni àwọn ọkunrin mẹta tí a rán sí mi láti Kesaria dé ilé tí mo wà. Ẹ̀mí wá sọ fún mi pé kí n bá wọn lọ láì kọminú. Mẹfa ninu àwọn arakunrin bá mi lọ. A bá wọ ilé ọkunrin náà. Ó sọ fún wa bí òun ti ṣe rí angẹli tí ó dúró ninu ilé òun tí ó sọ pé, ‘Ranṣẹ lọ sí Jọpa, kí o pe Simoni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Peteru wá. Òun ni yóo sọ ọ̀rọ̀ fún ọ nípa bí ìwọ ati ìdílé rẹ yóo ṣe ní ìgbàlà.’ Bí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ ni Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé wọn bí ó ti bà lé wa ní àkọ́kọ́. Ó mú mi ranti ọ̀rọ̀ Oluwa nígbà tí ó sọ pé, ‘Omi ni Johanu fi ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fun yín, ṣugbọn Ẹ̀mí Mímọ́ ni a óo fi ṣe ìwẹ̀nùmọ́ yín.’ Nítorí náà bí Ọlọrun bá fún wọn ní ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ kan náà bí ó ti fún àwa tí a gba Oluwa Jesu Kristi gbọ́, tèmi ti jẹ́, tí n óo wá dí Ọlọrun lọ́nà?” Nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, wọn kò tún ní ìkọminú mọ́ nípa ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Wọ́n bá ń yin Ọlọrun. Wọ́n ní, “Èyí ni pé Ọlọrun ti fún àwọn orílẹ̀-èdè yòókù náà ní anfaani láti ronupiwada kí wọ́n lè ní ìyè.” Àwọn tí ó túká nígbà inúnibíni tí ó ṣẹlẹ̀ ní àkókò Stefanu dé Fonike ní Kipru ati Antioku. Wọn kò bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀ ìyìn rere àfi àwọn Juu nìkan. Ṣugbọn nígbà tí àwọn kan ninu àwọn ará Kipru ati Kirene dé Antioku, wọ́n bá àwọn ará Giriki sọ̀rọ̀, wọ́n ń waasu Oluwa Jesu fún wọn. Agbára Oluwa hàn ninu iṣẹ́ wọn. Ọpọlọpọ eniyan ni wọ́n gbàgbọ́, tí wọ́n sì yipada sí Oluwa. Ìròyìn dé etí ìjọ tí ó wà ní Jerusalẹmu nípa wọn. Wọ́n bá rán Banaba sí Antioku. Nígbà tí ó dé, tí ó rí bí Ọlọrun ti ṣiṣẹ́ láàrin wọn, inú rẹ̀ dùn. Ó gba gbogbo wọn níyànjú pé kí wọ́n fi gbogbo ọkàn wọn dúró ti Oluwa pẹlu òtítọ́. Nítorí Banaba jẹ́ eniyan rere, tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, tí ó sì gbàgbọ́ tọkàntọkàn, ọ̀pọ̀ eniyan ni ó di onigbagbọ. Banaba bá wá Paulu lọ sí Tasu. Nígbà tí ó rí i, ó mú un wá sí Antioku; fún ọdún kan gbáko ni àwọn mejeeji fi wà pẹlu ìjọ, tí wọn ń kọ́ ọpọlọpọ eniyan lẹ́kọ̀ọ́. Ní Antioku ni a ti kọ́ pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Kristi ní “Kristẹni.” Ní àkókò náà, àwọn wolii kan wá láti Jerusalẹmu sí Antioku. Ọ̀kan ninu wọn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Agabu bá dìde. Ẹ̀mí gbé e láti sọ pé ìyàn ńlá yóo mú ní gbogbo ayé. (Èyí ṣẹlẹ̀ ní ayé ọba Kilaudiu.) Ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Kristi bá pinnu pé olukuluku àwọn yóo sa gbogbo agbára rẹ̀ láti fi nǹkan ranṣẹ sí àwọn onigbagbọ tí ó ń gbé Judia. Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n kó nǹkan rán Banaba ati Saulu sí wọn. Ní àkókò náà Hẹrọdu ọba bẹ̀rẹ̀ sí ṣe inúnibíni sí àwọn kan ninu ìjọ. Ó bẹ́ Jakọbu arakunrin Johanu lórí. Nígbà tí ó rí i pé ó dùn mọ́ àwọn Juu, ó bá tún mú Peteru náà. Àkókò náà ni Àjọ̀dún Àìwúkàrà. Ó bá mú Peteru ó tì í mọ́lé. Ó fi í lé àwọn ọ̀wọ́ ọmọ-ogun mẹrin lọ́wọ́ láti máa ṣọ́ ọ; (ọmọ-ogun mẹrin ni ó wà ní ọ̀wọ́ kọ̀ọ̀kan). Hẹrọdu fẹ́ mú Peteru wá siwaju gbogbo eniyan fún ìdájọ́ lẹ́yìn Àjọ̀dún Ìrékọjá. Wọ́n bá sọ Peteru sẹ́wọ̀n, ṣugbọn gbogbo ìjọ ń fi tọkàntọkàn gbadura sí Ọlọrun nítorí rẹ̀. Ní òru, mọ́jú ọjọ́ tí Hẹrọdu ìbá mú Peteru wá fún ìdájọ́, Peteru sùn láàrin àwọn ọmọ-ogun meji, wọ́n fi ẹ̀wọ̀n meji dè é; àwọn ọmọ-ogun kan sì tún wà lẹ́nu ọ̀nà, tí wọn ń ṣọ́nà. Angẹli Oluwa kan bá yọ dé, ìmọ́lẹ̀ sì tàn ninu ilé náà. Angẹli náà bá rọra lu Peteru lẹ́gbẹ̀ẹ́, ó jí i, ó ní, “Dìde kíá.” Àwọn ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi de Peteru bá yọ bọ́ kúrò ní ọwọ́ rẹ̀, Angẹli náà sọ fún un pé, “Di ìgbànú rẹ, sì wọ sálúbàtà rẹ.” Peteru bá ṣe bí angẹli náà ti wí. Angẹli yìí tún sọ fún un pé, “Da aṣọ rẹ bora, kí o máa tẹ̀lé mi.” Ni Peteru bá tẹ̀lé e jáde. Kò mọ̀ pé òtítọ́ ni ohun tí ó ti ọwọ́ angẹli náà ṣẹlẹ̀, ó ṣebí àlá ni. Wọ́n kọjá ẹ̀ṣọ́ kinni ati ekeji, wọ́n wá dé ẹnu ọ̀nà ńlá onírin tí ó jáde sinu ìlú. Fúnra ìlẹ̀kùn yìí ni ó ṣí sílẹ̀ fún wọn. Wọ́n bá jáde sí ojú ọ̀nà kan. Lójú kan náà, angẹli bá rá mọ́ Peteru lójú. Ojú Peteru wá wálẹ̀. Ó ní, “Mo wá mọ̀ nítòótọ́ pé Oluwa ni ó rán angẹli rẹ̀ láti gbà mí lọ́wọ́ Hẹrọdu, ati láti yọ mí kúrò ninu ohun gbogbo tí àwọn Juu ti ń retí.” Nígbà tí ó rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó lọ sí ilé Maria ìyá Johanu tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Maku. Ọpọlọpọ eniyan ni ó péjọ sibẹ tí wọn ń gbadura. Nígbà tí Peteru kan ìlẹ̀kùn tí ó wà lójúde, ọdọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Roda wá láti ṣí i. Nígbà tí ó gbọ́ ohùn Peteru, inú rẹ̀ dùn tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi dúró ṣí ìlẹ̀kùn; ṣugbọn ó sáré lọ sinu ilé, ó lọ sọ pé Peteru wà lóde lẹ́nu ọ̀nà. Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bú u pé, “Orí rẹ dàrú!” Ṣugbọn ó ṣá tẹnumọ́ ọn pé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí. Wọ́n wá sọ pé, “A jẹ́ pé angẹli rẹ̀ ni!” Ṣugbọn Peteru tún ń kanlẹ̀kùn. Nígbà tí wọ́n ṣí i, tí wọ́n rí i, ẹnu yà wọ́n. Ó bá fi ọwọ́ ṣe àmì sí wọn kí wọ́n dákẹ́; ó ròyìn fún wọn bí Oluwa ti ṣe mú òun jáde kúrò lẹ́wọ̀n. Ó ní kí wọn ròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Jakọbu ati fún àwọn arakunrin yòókù. Ó bá jáde, ó lọ sí ibòmíràn. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ìdààmú ńlá bá àwọn ọmọ-ogun. Wọn kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Peteru. Hẹrọdu wá Peteru títí, ṣugbọn kò rí i. Lẹ́yìn tí ó ti wádìí lẹ́nu àwọn ẹ̀ṣọ́ tán, ó ní kí wọ́n pa wọ́n. Ni Hẹrọdu bá kúrò ní Judia, ó lọ sí Kesaria, ó lọ gbé ibẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. Inú bí Hẹrọdu pupọ sí àwọn ará Tire ati Sidoni. Àwọn ará ìlú wọnyi bá fi ohùn ṣọ̀kan, wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Wọ́n tu Bilasitu tíí ṣe ìjòyè ọba tí ó ń mójútó ààfin lójú, wọ́n ń bẹ̀bẹ̀ pé kí ọba má bínú sí àwọn nítorí láti ilé ọba ni wọ́n ti ń rí oúnjẹ jẹ. Nígbà tí ó di ọjọ́ tí ọba dá fún wọn, Hẹrọdu yọ dé pẹlu aṣọ ìgúnwà rẹ̀, ó jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀. Ó wá bá àwọn eniyan náà sọ̀rọ̀. Ni àwọn eniyan náà bá ń kígbe pé, “Ohùn Ọlọrun nìyí, kì í ṣe ti eniyan!” Lẹsẹkẹsẹ angẹli Oluwa bá lù ú pa, nítorí kò fi ògo fún Ọlọrun. Ni ìdin bá jẹ ẹ́ pa. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun bẹ̀rẹ̀ sí fìdí múlẹ̀ sí i, ó sì túbọ̀ ń tàn káàkiri. Nígbà tí Banaba ati Saulu parí iṣẹ́ tí a rán wọn, wọ́n pada láti Jerusalẹmu, wọ́n mú Johanu tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Maku lọ́wọ́. Àwọn wolii ati àwọn olùkọ́ wà ninu ìjọ tí ó wà ní Antioku. Ninu wọn ni Banaba ati Simeoni tí wọn ń pè ní Adúláwọ̀ wà, ati Lukiusi ará Kirene, ati Manaeni tí wọ́n jọ tọ́ dàgbà pẹlu Hẹrọdu baálẹ̀, ati Saulu. Bí wọ́n ti jọ ń sin Oluwa, tí wọ́n ń gbààwẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ sọ fún wọn pé, “Ẹ ya Banaba ati Saulu sọ́tọ̀ fún mi, fún iṣẹ́ pataki kan tí mo ti pè wọ́n fún.” Lẹ́yìn tí wọ́n ti gbààwẹ̀, tí wọ́n sì gbadura, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn lórí, wọ́n sì ní kí wọ́n máa lọ. Lẹ́yìn tí Ẹ̀mí Mímọ́ ti fi iṣẹ́ lé àwọn mejeeji lọ́wọ́, wọ́n lọ sí Selesia. Láti ibẹ̀ wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Kipru. Nígbà tí wọ́n dé Salami, wọ́n waasu ọ̀rọ̀ Ọlọrun ninu àwọn ilé ìpàdé àwọn Juu. Wọ́n mú Johanu lọ́wọ́ kí wọn lè máa rí i rán níṣẹ́. Wọ́n la erékùṣù náà kọjá, wọ́n dé Pafọsi. Níbẹ̀ ni wọ́n rí ọkunrin Juu kan, tí ó ń pidán, tí ó fi ń tú àwọn eniyan jẹ. Orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ba-Jesu. Ọkunrin yìí ń ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ gomina ilẹ̀ náà, tí ń jẹ́ Segiu Paulu. Gomina yìí jẹ́ olóye eniyan. Ó ranṣẹ pe Banaba ati Saulu nítorí ó fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ṣugbọn Elimasi, tí ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀ jẹ́ onídán, takò wọ́n. Ó ń wá ọ̀nà láti yí ọkàn gomina pada kúrò ninu igbagbọ. Ẹ̀mí Mímọ́ bá gbé Saulu, tí a tún ń pè ní Paulu. Ó tẹjú mọ́ onídán náà, ó ní, “Ìwọ yìí, tí ó jẹ́ kìkì oríṣìíríṣìí ẹ̀tàn ati ìwà burúkú! Ìwọ ọmọ èṣù yìí! Ọ̀tá gbogbo nǹkan tí ó dára! O kò ní yé yí ọ̀nà títọ́ Oluwa po! Ọwọ́ Oluwa tẹ̀ ọ́ nisinsinyii. Ojú rẹ yóo fọ́, o kò ní lè rí oòrùn fún ìgbà kan!” Lójú kan náà, ìkùukùu dúdú dà bò ó. Ó bá ń tá ràrà, ó ń wá ẹni tí yóo fà á lọ́wọ́ kiri. Nígbà tí gomina rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó gbàgbọ́; nítorí pé ẹ̀kọ́ nípa Oluwa yà á lẹ́nu. Nígbà tí Paulu ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kúrò ní Pafọsi, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí ìlú Pega ní ilẹ̀ Pamfilia. Johanu fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀, ó pada lọ sí Jerusalẹmu. Wọ́n la ilẹ̀ náà kọjá láti Pega títí wọ́n fi dé ìlú Antioku lẹ́bàá ilẹ̀ Pisidia. Wọ́n lọ sí ilé ìpàdé àwọn Juu ní Ọjọ́ Ìsinmi, wọ́n bá jókòó. Lẹ́yìn tí wọ́n ti ka Ìwé Mímọ́, láti inú Ìwé Òfin Mose ati Ìwé àwọn wolii, àwọn olóyè ilé ìpàdé àwọn Juu sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin arakunrin, bí ẹ bá ní ọ̀rọ̀ ìyànjú fún àwọn eniyan, ẹ sọ ọ́.” Ni Paulu bá dìde, ó gbé ọwọ́ sókè, ó ní: “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli ati ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sin Ọlọrun wa, ẹ fetí sílẹ̀. Ọlọrun àwọn eniyan yìí, eniyan Israẹli, yan àwọn baba wa. Nígbà tí wọn ń gbé ilẹ̀ Ijipti bí àlejò, Ọlọrun sọ wọ́n di eniyan ńlá. Ó fi agbára ńlá rẹ̀ hàn nígbà tí ó mú wọn jáde kúrò ní Ijipti. Fún nǹkan bí ogoji ọdún ni ó fi ń kẹ́ wọn ní aṣálẹ̀. Orílẹ̀-èdè meje ni ó parẹ́ ní ilẹ̀ Kenaani nítorí tiwọn, ó sì jẹ́ kí wọ́n jogún ilẹ̀ wọn, fún nǹkan bí irinwo ọdún ó lé aadọta (450). “Lẹ́yìn èyí ó fún wọn ní àwọn onídàájọ́ títí di àkókò wolii Samuẹli. Lẹ́yìn náà wọ́n bèèrè fún ọba; Ọlọrun bá fún wọn ní Saulu ọmọ Kiṣi, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini. Ó jọba fún ogoji ọdún. Nígbà tí Ọlọrun yọ ọ́ lóyè, ó gbé Dafidi dìde fún wọn bí ọba. Ọlọrun jẹ́rìí sí ìwà rẹ̀ nígbà tí ó sọ pé, ‘Mo rí i pé Dafidi ọmọ Jese jẹ́ ẹni tí ọkàn mi ń fẹ́, ẹni tí yóo ṣe ohun gbogbo bí mo ti fẹ́.’ Láti inú ìran rẹ̀ ni Ọlọrun ti gbé Jesu dìde bí Olùgbàlà fún Israẹli gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí. Kí Jesu tó yọjú, Johanu ti ń waasu fún gbogbo àwọn eniyan Israẹli pé kí wọ́n ṣe ìrìbọmi bí àmì pé wọ́n ronupiwada. Nígbà tí Johanu fẹ́rẹ̀ dópin iṣẹ́ rẹ̀, ó ní, ‘Ta ni ẹ rò pé mo jẹ́? Èmi kì í ṣe ẹni tí ẹ rò. Ẹnìkan ń bọ̀ lẹ́yìn mi, ẹni tí n kò tó tú okùn bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀.’ “Ẹ̀yin arakunrin, ìran Abrahamu, ati ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sin Ọlọrun, àwa ni a rán iṣẹ́ ìgbàlà yìí sí. Àwọn tí ó ń gbé Jerusalẹmu ati àwọn olóyè wọn, wọn kò mọ ẹni tí Jesu jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ohun tí àwọn wolii ń sọ kò yé wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ni wọ́n ń kà á. Wọ́n mú àkọsílẹ̀ wọnyi ṣẹ nígbà tí wọ́n dá a lẹ́bi ikú. Láìjẹ́ pé wọ́n rí ohunkohun tí ó fi jẹ̀bi ikú, wọ́n ní kí Pilatu pa á. Nígbà tí wọ́n ti parí ohun gbogbo tí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé yóo ṣẹlẹ̀ sí i, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti orí igi agbelebu, wọ́n tẹ́ ẹ sinu ibojì. Ṣugbọn Ọlọrun jí i dìde kúrò ninu òkú. Fún ọpọlọpọ ọjọ́ ni ó fi ara hàn fún àwọn tí wọ́n bá a wá sí Jerusalẹmu láti Galili. Àwọn ni ẹlẹ́rìí fún gbogbo eniyan pé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí. A wá mú ìyìn rere wá fun yín pé ìlérí tí Ọlọrun ṣe fún àwọn baba wa ti ṣẹ, fún àwọn ọmọ wa, nígbà tí ó jí Jesu dìde, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ninu Orin Dafidi keji pé, ‘Ọmọ mi ni ọ́, lónìí yìí ni mo bí ọ.’ *** Ní ti pé ó jí i dìde kúrò ninu òkú, tí kò pada sí ipò ìdíbàjẹ́ mọ́, ohun tí ó sọ ni pé, ‘Èmi yóo fun yín ní ohun tí mo bá Dafidi pinnu.’ Bẹ́ẹ̀ ni ó tún sọ níbòmíràn pé, ‘O kò ní jẹ́ kí Ẹni ọ̀wọ̀ rẹ mọ ìdíbàjẹ́.’ Nítorí nígbà tí Dafidi ti sin ìran tirẹ̀ tán gẹ́gẹ́ bí ète Ọlọrun, ó sun oorun ikú, ó lọ bá àwọn baba rẹ̀, ara rẹ̀ rà nílẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí Ọlọrun jí dìde kò ní ìrírí ìdíbàjẹ́. Nítorí náà, ẹ̀yin ará, kí ó hàn si yín pé nítorí ẹni yìí ni a ṣe ń waasu ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fun yín. Ọpẹ́lọpẹ́ ẹni yìí ni a fi dá gbogbo ẹni tí ó bá gbàgbọ́ láre, àwọn tí Òfin Mose kò lè dá láre. *** Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra kí ohun tí a kọ sílẹ̀ ninu ìwé àwọn wolii má baà dé ba yín: ‘Ẹ wò ó, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn, kí ó yà yín lẹ́nu, kí ẹ sì parun! Nítorí n óo ṣe iṣẹ́ kan ní àkókò yín, tí ẹ kò ní gbàgbọ́ bí ẹnìkan bá ròyìn rẹ̀ fun yín.’ ” Bí Paulu ati Banaba ti ń jáde lọ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan ń bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n tún pada wá bá wọn sọ irú ọ̀rọ̀ yìí ní ọ̀sẹ̀ tí ó ń bọ̀. Nígbà tí ìpàdé túká, ọpọlọpọ àwọn Juu ati àwọn tí wọ́n ti di ẹlẹ́sìn àwọn Juu ń tẹ̀lé Paulu ati Banaba. Àwọn òjíṣẹ́ mejeeji yìí tún ń bá wọn sọ̀rọ̀, wọ́n ń gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n dúró láì yẹsẹ̀ ninu oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun. Nígbà tí ó di Ọjọ́ Ìsinmi keji, ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìlú ni ó péjọ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Oluwa. Nígbà tí àwọn Juu rí ọ̀pọ̀ eniyan, owú mú kí inú bí wọn. Wọ́n bá ń bu ẹnu àtẹ́ lu ohun tí Paulu ń sọ; wọ́n ń sọ ìsọkúsọ sí wọn. Paulu ati Banaba wá fi ìgboyà sọ pé, “Ẹ̀yin ni a níláti kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọrun fún. Ṣugbọn nígbà tí ẹ kọ̀ ọ́, tí ẹ kò ka ara yín yẹ fún ìyè ainipẹkun, àwa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn tí kì í ṣe Juu. Nítorí bẹ́ẹ̀ ni Oluwa pa láṣẹ fún wa nígbà tí ó sọ pé: ‘Mo ti fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, kí ìgbàlà mi lè dé òpin ilẹ̀ ayé.’ ” Nígbà tí àwọn tí kì í ṣe Juu gbọ́, inú wọn dùn. Wọ́n dúpẹ́ fún ọ̀rọ̀ Oluwa. Gbogbo àwọn tí a ti yàn láti ní ìyè ainipẹkun bá gbàgbọ́. Ọ̀rọ̀ Oluwa tàn ká gbogbo ilẹ̀ náà. Ṣugbọn àwọn Juu rú àwọn gbajúmọ̀ obinrin olùfọkànsìn sókè, ati àwọn eniyan pataki-pataki ní ìlú, ni wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí Paulu ati Banaba. Wọ́n lé wọn jáde kúrò ní agbègbè wọn. Ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà bá gbọn eruku ẹsẹ̀ wọn sílẹ̀ bí ẹ̀rí sí àwọn ará ìlú náà, wọ́n bá lọ sí Ikoniomu. Ayọ̀ kún ọkàn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu. Bẹ́ẹ̀ ni Ẹ̀mí Mímọ́ sì kún inú wọn. Nígbà tí wọ́n dé Ikoniomu, wọ́n lọ sí ilé ìpàdé àwọn Juu gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn. Wọ́n sọ̀rọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ọpọlọpọ ninu àwọn Juu ati àwọn Giriki fi gba Jesu gbọ́. Àwọn Juu tí kò gbà pé Jesu ni Mesaya wá gbin èrò burúkú sí ọkàn àwọn tí kì í ṣe Juu, wọ́n rú wọn sókè sí àwọn onigbagbọ. Paulu ati Banaba pẹ́ níbẹ̀. Wọ́n ń sọ̀rọ̀ ní gbangba, ẹ̀rù kò sì bà wọ́n nítorí wọ́n gbójú lé Oluwa tí ó jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ nípa iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu tí ó ń ti ọwọ́ wọn ṣe. Ìyapa bẹ́ sáàrin àwọn eniyan ninu ìlú; àwọn mìíràn fara mọ́ àwọn Juu, àwọn mìíràn fara mọ́ àwọn aposteli. Àwọn Juu ati àwọn tí kì í ṣe Juu pẹlu àwọn ìjòyè wọn dábàá láti ṣe wọ́n lọ́ṣẹ́, wọ́n fẹ́ sọ wọ́n ní òkúta pa. Nígbà tí àwọn aposteli mọ̀, wọ́n sálọ sí Listira ati Dabe, ìlú meji ní Likaonia, ati àwọn agbègbè wọn. Wọ́n bá ń waasu ìyìn rere níbẹ̀. Ọkunrin kan wà ní ìjókòó ní Listira tí ó yarọ. Láti ìgbà tí wọ́n ti bí i ni ó ti yarọ, kò fi ẹsẹ̀ rẹ̀ rìn rí. Ọkunrin yìí fetí sílẹ̀ bí Paulu ti ń sọ̀rọ̀. Paulu wá tẹjú mọ́ ọn lára, ó rí i pé ó ní igbagbọ pé wọ́n lè mú òun lára dá. Ó bá kígbe sókè, ó ní, “Dìde, kí o dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ bí eniyan.” Ni ọkunrin arọ náà bá fò sókè, ó bá ń rìn. Nígbà tí àwọn eniyan rí ohun tí Paulu ṣe, wọ́n kígbe ní èdè Likaonia pé, “Àwọn oriṣa ti di eniyan, wọ́n tọ̀run wá sáàrin wa!” Wọ́n pe Banaba ní Seusi, wọ́n pe Paulu ní Herime nítorí òun ni ó ń ṣe ògbifọ̀. Ní òde kí á tó wọ odi ìlú ni tẹmpili Seusi wà. Baba olórìṣà Seusi bá mú mààlúù ati òdòdó jìngbìnnì, òun ati ọpọlọpọ èrò, wọ́n ń bọ̀ lẹ́nu odi ìlú níbi tí pẹpẹ Seusi wà, wọ́n fẹ́ wá bọ wọ́n. Nígbà tí Banaba aposteli ati Paulu aposteli gbọ́, wọ́n fa ẹ̀wù wọn ya, wọ́n bá pa kuuru mọ́ àwọn èrò, wọ́n ń kígbe pé, “Ẹ̀yin eniyan, kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe irú eléyìí? Eniyan bíi yín ni àwa náà. À ń waasu fun yín pé kí ẹ yipada kúrò ninu àwọn ohun asán wọnyi, kí ẹ sin Ọlọrun alààyè, ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé, ati òkun ati ohun gbogbo tí ó wà ninu wọn. Ní ìgbà ayé àwọn tí ó ti kọjá, ó jẹ́ kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè máa ṣe ohun tí ó wù wọ́n. Sibẹ kò ṣàì fi àmì ara rẹ̀ hàn: ó ń ṣe iṣẹ́ rere, ó ń rọ òjò fun yín láti ọ̀run, ó ń mú èso jáde lásìkò, ó ń fun yín ní oúnjẹ, ó tún ń mú inú yín dùn.” Pẹlu gbogbo ọ̀rọ̀ yìí, agbára-káká ni wọn kò fi jẹ́ kí àwọn eniyan bọ wọ́n. Ṣugbọn àwọn Juu dé láti Antioku ati Ikoniomu, wọ́n yí ọkàn àwọn eniyan pada, wọ́n sọ Paulu ní òkúta, wọ́n sì wọ́ ọ lọ sẹ́yìn odi, wọ́n ṣebí ó ti kú. Ṣugbọn àwọn onigbagbọ pagbo yí i ká títí ó fi dìde tí ó sì wọ inú ìlú lọ. Ní ọjọ́ keji ó gbéra lọ sí Dabe pẹlu Banaba. Wọ́n waasu ìyìn rere ní ìlú náà, àwọn eniyan pupọ sì di onigbagbọ. Wọ́n bá pada sí Listira ati Ikoniomu ati Antioku ní Pisidia. Wọ́n ń mú àwọn onigbagbọ lọ́kàn le pé kí wọ́n dúró ṣinṣin ninu igbagbọ. Wọ́n ń fi yé wọn pé kí eniyan tó wọ ìjọba Ọlọrun, ó níláti ní ọpọlọpọ ìṣòro. Wọ́n yan àgbà ìjọ fún wọn ninu ìjọ kọ̀ọ̀kan. Nígbà tí wọ́n ti gbadura, tí wọ́n sì ti gbààwẹ̀, wọ́n fi wọ́n lé ọwọ́ Oluwa tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lé. Wọ́n wá gba Pisidia kọjá lọ sí Pamfilia. Nígbà tí wọ́n ti waasu ìyìn rere ní Pega, wọ́n lọ sébùúté ní Atalia. Wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi láti ibẹ̀ lọ sí Antioku ní Siria níbi tí wọ́n ti kọ́ fi wọ́n sábẹ́ ojurere Ọlọrun fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ parí. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, wọ́n pe gbogbo ìjọ jọ, wọ́n ròyìn ohun gbogbo tí Ọlọrun tọwọ́ wọn ṣe ati bí Ọlọrun ti ṣínà fún àwọn tí kì í ṣe Juu láti gbàgbọ́. Wọ́n dúró níbẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn onigbagbọ fún ìgbà pípẹ́. Àwọn kan wá láti Judia tí wọn ń kọ́ àwọn onigbagbọ pé, “Bí ẹ kò bá kọlà gẹ́gẹ́ bí àṣà ati Òfin Mose, a kò lè gbà yín là!” Ó di ọ̀rọ̀ líle ati àríyànjiyàn ńlá láàrin àwọn ati Paulu ati Banaba. Ni ìjọ bá pinnu pé kí Paulu ati Banaba ati àwọn mìíràn láàrin wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn aposteli ati àwọn alàgbà ní Jerusalẹmu láti yanjú ọ̀rọ̀ náà. Àwọn ìjọ sìn wọ́n sọ́nà, wọ́n wá gba Fonike ati Samaria kọjá, wọ́n ń ròyìn gẹ́gẹ́ bí àwọn tí kì í ṣe Juu ṣe ń yipada di onigbagbọ. Èyí mú kí inú gbogbo àwọn onigbagbọ tí wọ́n gbọ́ dùn pupọ. Nígbà tí wọ́n dé Jerusalẹmu, gbogbo ìjọ, ati àwọn aposteli ati àwọn àgbààgbà gbà wọ́n tọwọ́-tẹsẹ̀. Wọ́n wá ròyìn ohun gbogbo tí Ọlọrun ti ṣe fún wọ́n. Àwọn kan láti inú ẹgbẹ́ àwọn Farisi tí wọ́n jẹ́ onigbagbọ wá dìde. Wọ́n ní, “Dandan ni pé kí á kọ àwọn tí kì í ṣe Juu tí ó bá fẹ́ di onigbagbọ nílà, kí á sì pàṣẹ fún wọn láti máa pa Òfin Mose mọ́.” Gbogbo àwọn aposteli ati àwọn àgbààgbà bá péjọ láti rí sí ọ̀rọ̀ yìí. Àríyànjiyàn pupọ ni ó bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn. Peteru bá dìde, ó ní, “Ẹ̀yin arakunrin, ẹ̀yin gan-an mọ̀ pé ní àtijọ́ Ọlọrun yàn mí láàrin yín pé láti ẹnu mi ni àwọn tí kì í ṣe Juu yóo ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ìyìn rere, kí wọ́n lè gba Jesu gbọ́. Ọlọrun olùmọ̀ràn ọkàn fún wọn ní ìwé ẹ̀rí nígbà tí ó fún wọn ní Ẹ̀mí Mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ó ti fún wa. Kò fi ìyàtọ̀ kankan sáàrin àwa ati àwọn; ó wẹ ọkàn wọn mọ́ nítorí wọ́n gba Jesu gbọ́. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ní ṣe tí ẹ fi fẹ́ dán Ọlọrun wò, tí ẹ fẹ́ gbé àjàgà tí àwọn baba wa ati àwa náà kò tó rù, rù àwọn ọmọ-ẹ̀yìn? A gbàgbọ́ pé nípa oore-ọ̀fẹ́ Jesu Oluwa ni a fi gbà wá là, gẹ́gẹ́ bí a ti fi gba àwọn náà là.” Ńṣe ni gbogbo àwùjọ dákẹ́ jẹ́ẹ́. Wọ́n wá fetí sílẹ̀ sí ohun tí Banaba ati Paulu níí sọ nípa iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu tí Ọlọrun tọwọ́ wọn ṣe láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu. Lẹ́yìn tí wọ́n ti parí ọ̀rọ̀ tí wọ́n níí sọ, Jakọbu bá fèsì pé, “Ẹ̀yin arakunrin, ẹ fetí sí mi. Simoni ti ròyìn ọ̀nà tí Ọlọrun kọ́kọ́ fi ṣe ìkẹ́ àwọn tí kì í ṣe Juu kí ó lè mú ninu wọn fi ṣe eniyan tirẹ̀. Ọ̀rọ̀ àwọn wolii bá èyí mu, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Lẹ́yìn èyí, n óo tún ilé Dafidi tí ó ti wó kọ́. N óo tún ahoro rẹ̀ mọ, n óo sì gbé e ró. Báyìí ni gbogbo àwọn tí kì í ṣe Juu yóo máa wá Oluwa, ati gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tí mo ti pè láti jẹ́ tèmi. Bẹ́ẹ̀ ni Oluwa wí, ó sì jẹ́ kí á mọ ọ̀rọ̀ náà láti ìgbà àtijọ́-tijọ́.’ “Ní tèmi, èrò mi ni pé kí á má tún yọ àwọn tí kì í ṣe Juu tí wọ́n yipada sí Ọlọrun lẹ́nu mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀ kí á kọ ìwé sí wọn pé kí wọ́n takété sí ohunkohun tí ó bá ti di àìmọ́ nítorí pé a ti fi rúbọ sí oriṣa; kí wọn má ṣe àgbèrè, kí wọn má jẹ ẹran tí a lọ́ lọ́rùn pa, kí wọn má sì jẹ ẹ̀jẹ̀. Nítorí láti ìgbà àtijọ́ ni wọ́n ti ń ké òkìkí Mose láti ìlú dé ìlú tí wọn sì ń ka ìwé rẹ̀ ninu gbogbo ilé ìpàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.” Àwọn aposteli ati àwọn àgbà ìjọ pẹlu gbogbo ìjọ wá pinnu láti yan àwọn eniyan láàrin wọn, láti rán lọ sí Antioku pẹlu Paulu ati Banaba. Wọ́n bá yan Juda tí à ń pè ní Basaba ati Sila, tí wọn jẹ́ aṣaaju láàrin àwọn onigbagbọ. Wọ́n fi ìwé rán wọn, pé: “Àwa aposteli ati àwa alàgbà kí ẹ̀yin tí kì í ṣe Juu ní Antioku, Siria ati Silisia; a kí yín bí arakunrin sí arakunrin. A gbọ́ pé àwọn kan láti ọ̀dọ̀ wa ń fi ọ̀rọ̀ yọ yín lẹ́nu, wọn kò jẹ́ kí ọkàn yín balẹ̀. A kò rán wọn níṣẹ́. A ti wá pinnu, gbogbo wa sì fohùn sí i, a wá yan àwọn eniyan láti rán si yín pẹlu Banaba ati Paulu, àwọn àyànfẹ́ wa, àwọn tí wọ́n ti fi ẹ̀mí wọn lélẹ̀ nítorí orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi. Nítorí náà a rán Juda ati Sila, láti fẹnu sọ ohun kan náà tí a kọ sinu ìwé fun yín. Ẹ̀mí Mímọ́ ati àwa náà pinnu pé kí á má tún di ẹrù tí ó wúwo jù le yín lórí mọ́, yàtọ̀ sí àwọn nǹkan pataki wọnyi: kí ẹ má jẹ ẹran tí a fi rúbọ sí oriṣa; kí ẹ má jẹ ẹ̀jẹ̀; kí ẹ má jẹ ẹran tí a lọ́ lọ́rùn pa; kí ẹ má ṣe àgbèrè. Bí ẹ bá takété sí àwọn nǹkan wọnyi, yóo dára. Ó dìgbà o!” Nígbà tí àwọn tí a rán kúrò, wọ́n dé Antioku, wọ́n pe gbogbo ìjọ, wọ́n fún wọn ní ìwé náà. Nígbà tí wọ́n kà á, inú wọn dùn sí ọ̀rọ̀ ìyànjú tí ó wà ninu rẹ̀. Juda ati Sila, tí wọ́n jẹ́ wolii fúnra wọn, tún fi ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ gba ẹgbẹ́ onigbagbọ náà níyànjú, wọ́n tún mú wọn lọ́kàn le. Wọ́n dúró fún ìgbà díẹ̀, ni àwọn ìjọ bá fi tayọ̀tayọ̀ rán wọn pada lọ sọ́dọ̀ àwọn tí ó rán wọn wá. [ Ṣugbọn Sila pinnu láti dúró níbẹ̀.] Ṣugbọn Paulu ati Banaba dúró ní Antioku, wọ́n ń kọ́ àwọn eniyan, àwọn ati eniyan pupọ mìíràn ń waasu ọ̀rọ̀ Oluwa. Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ Paulu wí fún Banaba pé, “Jẹ́ kí á pada lọ bẹ àwọn onigbagbọ wò ní gbogbo ìlú tí a ti waasu ọ̀rọ̀ Oluwa, kí a rí bí wọ́n ti ń ṣe.” Banaba fẹ́ mú Johanu tí à ń pè ní Maku lọ. Ṣugbọn Paulu kò rò pé ó yẹ láti mú un lọ, nítorí ó pada lẹ́yìn wọn ní Pamfilia, kò bá wọn lọ títí dé òpin iṣẹ́ náà. Àríyànjiyàn náà le tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi pínyà, tí olukuluku fi bá ọ̀nà rẹ̀ lọ. Banaba mú Maku, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Kipru. Paulu mú Sila ó bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ lẹ́yìn tí àwọn onigbagbọ ti fi í lé oore-ọ̀fẹ́ Oluwa lọ́wọ́. Ó gba Siria ati Silisia kọjá, ó ń mú àwọn ìjọ lọ́kàn le. Paulu dé Dabe ati Listira. Onigbagbọ kan tí ń jẹ́ Timoti wà níbẹ̀. Ìyá rẹ̀ jẹ́ Juu tí ó gba Jesu gbọ́; ṣugbọn Giriki ni baba rẹ̀. Àwọn arakunrin ní Listira ati Ikoniomu ròyìn Timoti yìí dáradára. Òun ni ó wu Paulu láti mú lọ sí ìrìn-àjò rẹ̀, nítorí náà, ó mú un, ó kọ ọ́ nílà nítorí àwọn Juu tí ó wà ní agbègbè ibẹ̀; nítorí gbogbo wọn ni wọ́n mọ̀ pé Giriki ni baba rẹ̀. Bí wọ́n ti ń lọ láti ìlú dé ìlú, wọ́n ń sọ fún wọn nípa ìpinnu tí àwọn aposteli ati àwọn àgbààgbà ní Jerusalẹmu ṣe, wọ́n sì ń gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n pa wọ́n mọ́. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìjọ túbọ̀ ń lágbára sí i ninu igbagbọ, tí wọ́n sì ń pọ̀ sí i ní iye lojoojumọ. Wọ́n gba ilẹ̀ Firigia ati Galatia kọjá. Ẹ̀mí Mímọ́ kò gbà wọ́n láàyè láti lọ waasu ọ̀rọ̀ Oluwa ní Esia. Nígbà tí wọ́n súnmọ́ Misia, wọ́n gbìyànjú láti lọ sí Bitinia. Ṣugbọn Ẹ̀mí Jesu kò gbà fún wọn. Nígbà tí wọ́n ti la Misia kọjá, wọ́n dé Tiroasi. Nígbà tí ó di alẹ́, Paulu rí ìran kan. Ó rí ọkunrin kan ará Masedonia tí ó dúró, tí ó ń bẹ̀ ẹ́ pé, “Sọdá sí Masedonia níbí kí o wá ràn wá lọ́wọ́.” Gbàrà tí ó rí ìran náà, a wá ọ̀nà láti lọ sí Masedonia; a pinnu pé Ọlọrun ni ó pè wá láti lọ waasu fún wọn níbẹ̀. Nígbà tí a wọ ọkọ̀ láti Tiroasi, a lọ tààrà sí Samotirake. Ní ọjọ́ keji a gúnlẹ̀ ní Neapoli. Láti ibẹ̀, a lọ sí Filipi tíí ṣe olú-ìlú ilẹ̀ Masedonia. Àwọn ará Romu ni wọ́n tẹ ìlú yìí dó. A bá wà níbẹ̀ fún ọjọ́ mélòó kan. Ní Ọjọ́ Ìsinmi a jáde lọ sẹ́yìn odi ìlú lẹ́bàá odò, níbi tí a rò pé a óo ti rí ibi tí wọn máa ń gbadura. A bá jókòó, a bá àwọn obinrin tí ó péjọ níbẹ̀ sọ̀rọ̀. Obinrin kan wà níbẹ̀ tí ó ń jẹ́ Lidia, ará Tiatira, tí ó ń ta aṣọ àlàárì. Ó jẹ́ ẹnìkan tí ó ń sin Ọlọrun. Ó fetí sílẹ̀, Ọlọrun ṣí i lọ́kàn láti gba ohun tí Paulu ń sọ. Òun ati àwọn ará ilé rẹ̀ gba ìrìbọmi. Lẹ́yìn náà, ó bẹ̀ wá pé, bí a bá gbà pé òun jẹ́ onigbagbọ nítòótọ́, kí á máa bọ̀ ní ilé òun kí á máa bá àwọn gbé. Ó tẹnu mọ́ ọn títí a fi gbà. Ní ọjọ́ kan, bí a ti ń lọ sí ibi adura, a pàdé ọdọmọbinrin kan tí ó ní ẹ̀mí àfọ̀ṣẹ. Ó ti ń mú èrè pupọ wá fún àwọn olówó rẹ̀ nípa àfọ̀ṣẹ rẹ̀. Ó ń tẹ̀lé Paulu ati àwa náà, ó ń kígbe pé, “Àwọn ọkunrin yìí ni iranṣẹ Ọlọrun Ọ̀gá Ògo; àwọn ni wọ́n ń waasu ọ̀nà ìgbàlà fun yín.” Ó ń ṣe báyìí fún ọjọ́ pupọ. Nígbà tí ara Paulu kò gbà á mọ́, ó yipada, ó sọ fún ẹ̀mí náà pé, “Mo pàṣẹ fún ọ ní orúkọ Jesu, jáde kúrò ninu rẹ̀.” Ni ó bá jáde lẹ́sẹ̀ kan náà. Nígbà tí àwọn olówó ọdọmọbinrin náà rí i pé ọ̀nà oúnjẹ wọ́n ti dí, wọ́n ki Paulu ati Sila mọ́lẹ̀, wọ́n fà wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ ní ọjà. Wọ́n mú wọn wá siwaju àwọn adájọ́. Wọ́n ní, “Juu ni àwọn ọkunrin wọnyi, wọ́n sì ń da ìlú wa rú. Wọ́n ń kọ́ àwọn eniyan ní àṣà tí kò tọ́ fún wa láti gbà tabi láti ṣe nítorí ará Romu ni wá.” Ni àwọn eniyan bá bẹ̀rẹ̀ sí lu Paulu ati Sila. Àwọn adájọ́ fa aṣọ ya mọ́ wọn lára, wọ́n pàṣẹ pé kí wọ́n nà wọ́n. Nígbà tí wọ́n ti nà wọ́n dáradára, wọ́n bá sọ wọ́n sẹ́wọ̀n. Wọ́n pàṣẹ fún ẹni tí ó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n pé kí ó ṣọ́ wọn dáradára. Nígbà tí ó ti gba irú àṣẹ báyìí, ó sọ wọ́n sinu àtìmọ́lé ti inú patapata, ó tún fi ààbà kan ẹsẹ̀ wọn mọ́ igi. Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́, Paulu ati Sila ń gbadura, wọ́n ń kọrin sí Ọlọrun. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n yòókù ń dẹtí sí wọn. Lójijì ni ilẹ̀ mì tìtì, tóbẹ́ẹ̀ tí ìpìlẹ̀ ilé ẹ̀wọ̀n mì. Lọ́gán gbogbo ìlẹ̀kùn ṣí; gbogbo ẹ̀wọ̀n tí a fi de àwọn ẹlẹ́wọ̀n sì tú. Nígbà tí ẹni tí ó ń ṣọ́ ilé ẹ̀wọ̀n jí lójú oorun, tí ó rí i pé ìlẹ̀kùn ilé ẹ̀wọ̀n ti ṣí, ó fa idà rẹ̀ yọ, ó fẹ́ pa ara rẹ̀, ó ṣebí àwọn ẹlẹ́wọ̀n ti sálọ ni. Paulu bá kígbe pè é, ó ní, “Má ṣe ara rẹ léṣe, nítorí gbogbo wa wà níhìn-ín.” Ẹni tí ń ṣọ́ ilé ẹ̀wọ̀n náà bá bèèrè iná, ó pa kuuru wọ inú iyàrá, ó ń gbọ̀n láti orí dé ẹsẹ̀. Ó wólẹ̀ níwájú Paulu ati Sila. Ó mú wọn jáde, ó ní, “Ẹ̀yin alàgbà, kí ni ó yẹ kí n ṣe kí n lè là?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Gba Jesu Oluwa gbọ́, ìwọ ati ìdílé rẹ yóo sì là.” Wọ́n bá sọ ọ̀rọ̀ Oluwa fún òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀. Ní òru náà, ó mú wọn, ó wẹ ọgbẹ́ wọn. Lójú kan náà òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀ sì ṣe ìrìbọmi. Ó bá mú wọn wọ ilé, ó fún wọn ní oúnjẹ. Inú òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀ dùn pupọ nítorí ó ti gba Ọlọrun gbọ́. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn adájọ́ rán àwọn iranṣẹ sí ẹni tí ń ṣọ́ ilé ẹ̀wọ̀n pé, kí ó dá àwọn eniyan náà sílẹ̀. Ẹni tí ó ń ṣọ́ ilé ẹ̀wọ̀n náà bá lọ jíṣẹ́ fún Paulu pé, “Àwọn adájọ́ ti ranṣẹ pé kí á da yín sílẹ̀. Ẹ jáde kí ẹ máa lọ ní alaafia.” Ṣugbọn Paulu sọ fún wọn pé, “Wọ́n nà wá ní gbangba láì ká ẹ̀bi mọ́ wa lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ọmọ-ìbílẹ̀ Romu ni wá. Wọ́n sọ wá sẹ́wọ̀n, wọ́n wá fẹ́ tì wá jáde níkọ̀kọ̀. Rárá o! Kí àwọn fúnra wọn wá kó wa jáde.” Àwọn iranṣẹ tí àwọn adájọ́ rán wá lọ ròyìn ọ̀rọ̀ wọnyi fún wọn. Ẹ̀rù bà wọ́n nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ọmọ-ìbílẹ̀ Romu ni wọ́n jẹ́. Wọ́n bá wá, wọ́n bẹ̀ wọ́n. Wọ́n sìn wọ́n jáde, wọ́n bá rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n kúrò ninu ìlú. Nígbà tí wọ́n jáde kúrò lẹ́wọ̀n, wọ́n lọ sí ilé Lidia. Lẹ́yìn tí wọ́n rí àwọn onigbagbọ, tí wọ́n sì gbà wọ́n níyànjú, wọ́n kúrò níbẹ̀. Wọ́n kọjá ní Amfipoli ati Apolonia kí wọn tó dé Tẹsalonika. Ilé ìpàdé àwọn Juu kan wà níbẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí àṣà Paulu, ó wọ ibẹ̀ tọ̀ wọ́n lọ. Fún ọ̀sẹ̀ mẹta ni ó fi ń bá wọn fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ láti inú Ìwé Mímọ́. Ó ń ṣe àlàyé fún wọn, ó tún ń tọ́ka sí àkọsílẹ̀ inú Ìwé Mímọ́ láti fihàn pé dandan ni kí Mesaya jìyà, kí ó jinde kúrò ninu òkú. Lẹ́yìn náà ó sọ fún wọn pé, Mesaya yìí náà ni Jesu tí òun ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún wọn. Àwọn kan ninu wọn gbàgbọ́, wọ́n fara mọ́ Paulu ati Sila. Ọ̀pọ̀ ninu wọn jẹ́ Giriki, wọ́n ń sin Ọlọrun; pupọ ninu àwọn obinrin sì jẹ́ eniyan pataki-pataki. Ṣugbọn ara ta àwọn Juu nígbà tí wọ́n rí i pé àwọn eniyan pupọ gba ọ̀rọ̀ Paulu ati Sila. Wọ́n bá lọ mú ninu àwọn tí wọ́n ń fẹsẹ̀ wọ́lẹ̀ kiri, àwọn jàgídíjàgan, wọ́n kó wọn jọ. Wọ́n bá dá ìrúkèrúdò sílẹ̀ ninu ìlú. Wọ́n lọ ṣùrù bo ilé Jasoni, wọ́n ń wá Paulu ati Sila kí wọ́n lè fà wọ́n lọ siwaju àwọn ará ìlú. Nígbà tí wọn kò rí wọn, wọ́n fa Jasoni ati díẹ̀ ninu àwọn onigbagbọ lọ siwaju àwọn aláṣẹ ìlú. Wọ́n ń kígbe pé, “Àwọn tí wọn ń da gbogbo ayé rú nìyí; wọ́n ti dé ìhín náà. Jasoni sì ti gbà wọ́n sílé. Gbogbo wọn ń ṣe ohun tí ó lòdì sí àṣẹ Kesari. Wọ́n ní: ọba mìíràn wà, ìyẹn ni Jesu!” Ọkàn àwọn eniyan ati àwọn aláṣẹ ìlú dààmú nígbà tí wọ́n gbọ́ báyìí. Wọ́n bá gba owó ìdúró lọ́wọ́ Jasoni ati àwọn yòókù, wọ́n bá dá wọn sílẹ̀. Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, àwọn onigbagbọ tètè ṣe ètò láti mú Paulu ati Sila lọ sí Beria. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, wọ́n lọ sí ilé ìpàdé àwọn Juu. Àwọn yìí ṣe onínú rere ju àwọn Juu ti Tẹsalonika lọ. Wọ́n fi ìtara gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. Lojoojumọ ni wọ́n ń wá inú Ìwé Mímọ́ wò láti rí bí àwọn ohun tí wọ́n kọ́ wọn rí bẹ́ẹ̀. Pupọ ninu wọn gbàgbọ́, ati pupọ ninu àwọn Giriki tí wọ́n jẹ́ eniyan pataki-pataki, lọkunrin ati lobinrin. Ṣugbọn nígbà tí àwọn Juu ní Tẹsalonika mọ̀ pé Paulu ti tún waasu ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní Beria, wọ́n wá sibẹ láti ṣe màdàrú ati láti dá rúkèrúdò sílẹ̀. Lẹsẹkẹsẹ ni àwọn onigbagbọ bá ṣe ètò fún Paulu láti lọ sí èbúté. Ṣugbọn Sila ati Timoti dúró ní Beria. Àwọn tí ó sin Paulu lọ mú un dé Atẹni. Wọ́n wá gba ìwé pada fún Sila ati Timoti pé kí wọ́n tètè wá bá a. Nígbà tí Paulu ń dúró dè wọ́n ní Atẹni, ó rí ìlú náà bí ó ti kún fún ère oriṣa. Eléyìí sì dùn ún dọ́kàn. Nítorí náà, ó ń bá àwọn Juu ati àwọn olùfọkànsìn tí kì í ṣe Juu jiyàn ninu ilé ìpàdé ní ojoojumọ. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó ń ṣe láàrin ọjà, ó ń bá ẹnikẹ́ni tí ó bá wà nítòsí sọ̀rọ̀. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan ninu àwọn ọmọlẹ́yìn Epikurusi ati àwọn Sitoiki bẹ̀rẹ̀ sí bá a jiyàn. Àwọn kan ń sọ pé, “Kí ni aláhesọ yìí ń wí?” Àwọn mìíràn ní, “Ó jọ pé òjíṣẹ́ oriṣa àjèjì kan ni!” Nítorí ó ń waasu nípa Jesu ati ajinde. Ni wọ́n bá ní kí ó kálọ sí Òkè Areopagu. Wọ́n wá bi í pé, “Ǹjẹ́ a lè mọ ohun tí ẹ̀kọ́ titun tí ò ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí jẹ́? Nítorí ohun tí ò ń sọ ṣe àjèjì létí wa. A sì fẹ́ mọ ìtumọ̀ rẹ̀.” (Gbogbo àwọn ará Atẹni ní tiwọn, ati àwọn àlejò tí ó ń gbé ibẹ̀, kí wọn ṣá máa ròyìn nǹkan titun tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ̀lú ni iṣẹ́ tiwọn. Bí wọn bá ti gbọ́ èyí, ohun tí ó ń ṣe wọ́n tán.) Paulu bá dìde dúró láàrin ìgbìmọ̀ tí ó wà ní Òkè Areopagu, ó ní, “Ẹ̀yin ará Atẹni, ó hàn lọ́tùn-ún lósì sí ẹni tí ó bá wò ó pé ẹ kò fi ọ̀rọ̀ oriṣa ṣeré. Bí mo ti ń lọ tí mò ń bọ̀ ni mò ń fojú wo àwọn ohun tí ẹ̀ ń sìn. Mo rí pẹpẹ ìrúbọ kan tí ẹ kọ àkọlé báyìí sí ara rẹ̀ pé: ‘Sí Ọlọrun tí ẹnìkan kò mọ̀.’ Ohun tí ẹ kò mọ̀ tí ẹ̀ ń sìn, òun ni mò ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ fun yín. Ọlọrun tí ó dá ayé ati gbogbo nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀, Oluwa ọ̀run ati ayé, kì í gbé ilé oriṣa àfọwọ́kọ́; bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun tí kò ní, tí a óo sọ pé kí eniyan fún un, nítorí òun fúnra rẹ̀ ni ó ń fún gbogbo eniyan ní ẹ̀mí, èémí ati ohun gbogbo. Òun ni ó dá gbogbo orílẹ̀-èdè láti inú ẹnìkan ṣoṣo láti máa gbé gbogbo ilẹ̀ ayé. Kí ó tó dá wọn, ó ti ṣe ìpinnu tẹ́lẹ̀ nípa ìgbà tí wọn yóo gbé ní ayé ati ààlà ibi tí wọn yóo máa gbé. Ó dá wọn láti máa wá òun Ọlọrun, bí ó bá ṣeéṣe, kí wọ́n fọwọ́ kàn án, kí wọ́n rí i. Kò sì kúkú jìnnà sí ẹnìkan kan ninu wa. Nítorí ẹnìkan sọ níbìkan pé: ‘Ninu rẹ̀ ni à ń gbé, tí à ń rìn kiri, tí a wà láàyè.’ Àwọn kan ninu àwọn akéwì yín pàápàá ti sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀; wọ́n ní, ‘Ọmọ rẹ̀ ni a jẹ́.’ Nígbà tí a jẹ́ ọmọ Ọlọrun, kò yẹ kí á rò pé Ọlọrun dàbí ère wúrà, tabi fadaka, tabi òkúta, ère tí oníṣẹ́ ọnà ṣe pẹlu ọgbọ́n ati èrò eniyan. Ọlọrun ti fojú fo àkókò tí eniyan kò ní ìmọ̀ dá. Ṣugbọn ní àkókò yìí, ó pàṣẹ fún gbogbo eniyan ní ibi gbogbo láti ronupiwada. Nítorí ó ti yan ọjọ́ tí yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ gbogbo ayé nípa ọkunrin tí ó ti yàn. Ó fi òtítọ́ èyí han gbogbo eniyan nígbà tí ó jí ẹni náà dìde kúrò ninu òkú.” Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé òkú jinde, àwọn kan ń ṣe yẹ̀yẹ́, àwọn mìíràn ní, “A tún fẹ́ gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ yìí nígbà mìíràn.” Paulu bá jáde kúrò láàrin wọn. Àwọn kan ninu wọn bá fara mọ́ ọn, wọ́n sì gbàgbọ́. Ọ̀kan ninu wọn ni Dionisu, adájọ́ ní kóòtù Òkè Areopagu, ati obinrin kan tí ń jẹ́ Damarisi ati àwọn ẹlòmíràn pẹlu wọn. Lẹ́yìn èyí, Paulu kúrò ní Atẹni, ó lọ sí Kọrinti. Ó rí Juu kan níbẹ̀, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Akuila, ará Pọntu. Òun ati Pirisila iyawo rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ilẹ̀ Itali dé ni, nítorí ọba Kilaudiu pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn Juu kúrò ní ìlú Romu. Paulu bá lọ sọ́dọ̀ wọn. Nítorí pé iṣẹ́ kan náà ni wọ́n ń ṣe, Paulu lọ wọ̀ lọ́dọ̀ wọn, ó sì ń ṣiṣẹ́. Iṣẹ́ ọnà awọ tí wọ́n fi ń ṣe àgọ́ ni wọ́n ń ṣe. Ní gbogbo Ọjọ́ Ìsinmi, a máa bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀; ó fẹ́ yí àwọn Juu ati Giriki lọ́kàn pada. Nígbà tí Sila ati Timoti dé láti Masedonia, Paulu wá fi gbogbo àkókò rẹ̀ sílẹ̀ fún iwaasu, ó ń tẹnu mọ́ ọn fún àwọn Juu pé Jesu ni Mesaya. Ṣugbọn nígbà tí àwọn kan takò ó, tí wọn ń sọ ìsọkúsọ, ó gbọn ẹ̀wù rẹ̀ sí wọn lójú, ó ní, “Ẹ̀jẹ̀ yín wà lọ́rùn yín. Ọwọ́ tèmi mọ́. Láti ìgbà yìí lọ èmi yóo lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.” Ni ó bá kúrò níbẹ̀, ó wọ ilé ẹnìkan tí ó ń jẹ́ Titiu Jusitu, ẹnìkan tí ń sin Ọlọrun. Ilé rẹ̀ fẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹlu ilé ìpàdé àwọn Juu. Kirisipu, ẹni tí ń darí ètò ilé ìpàdé àwọn Juu gba Oluwa gbọ́ pẹlu gbogbo ilé rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni pupọ ninu àwọn ará Kọrinti; nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Oluwa, wọ́n gbàgbọ́, wọ́n bá ṣe ìrìbọmi. Ní alẹ́ ọjọ́ kan, Paulu rí ìran kan. Ninu ìran náà Oluwa sọ fún un pé, “Má bẹ̀rù, máa waasu, má dákẹ́. Nítorí n óo wà pẹlu rẹ. Kò sí ẹni tí yóo fọwọ́ kàn ọ́ láti ṣe ọ́ níbi. Nítorí mo ní eniyan pupọ ninu ìlú yìí.” Paulu gbé ààrin wọn fún ọdún kan ati oṣù mẹfa, ó ń kọ́ wọn ní ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ṣugbọn nígbà tí Galio di gomina Akaya, àwọn Juu fi ohùn ṣọ̀kan láti dìde sí Paulu. Wọ́n bá mú un lọ sí kóòtù níwájú Galio. Wọ́n ní, “Ọkunrin yìí ń kọ́ àwọn eniyan láti sin Ọlọrun ní ọ̀nà tí ó lòdì sí òfin.” Bí Paulu ti fẹ́ lanu láti fèsì, Galio sọ fún àwọn Juu pé, “Ẹ̀yin Juu, bí ó bá jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kan tabi ọ̀ràn burúkú kan ni ẹ mú wá, ǹ bá gbọ́ ohun tí ẹ ní sọ; ṣugbọn tí ó bá jẹ́ àríyànjiyàn nípa àwọn ọ̀rọ̀ tabi orúkọ, tabi òfin yín, ẹ lọ rí sí i fúnra yín. N kò fẹ́ dá irú ẹjọ́ bẹ́ẹ̀.” Ni ó bá lé wọn kúrò ní kóòtù. Ni gbogbo wọ́n bá mú Sositene, olórí ilé ìpàdé àwọn Juu, wọ́n ń lù ú níwájú kóòtù. Ṣugbọn Galio kò pé òun rí wọn. Paulu tún dúró fún ìgbà díẹ̀ sí i. Lẹ́yìn náà ó dágbére fún àwọn onigbagbọ, ó bá wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Siria; Pirisila ati Akuila bá a lọ. Paulu gé irun rẹ̀ ní ìlú Kẹnkiria nítorí pé ó ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan. Nígbà tí wọ́n dé Efesu, Paulu fi Pirisila ati Akuila sílẹ̀, ó lọ sinu ilé ìpàdé àwọn Juu, ó lọ bá àwọn Juu sọ̀rọ̀. Wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó dúró lọ́dọ̀ wọn fún àkókò díẹ̀ sí i, ṣugbọn kò gbà. Bí ó ti fẹ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó ní, “N óo tún pada wá sí ọ̀dọ̀ yín bí Ọlọrun bá fẹ́.” Ó bá kúrò ní Efesu. Nígbà tí ó gúnlẹ̀ ní Kesaria, ó lọ kí ìjọ ní Jerusalẹmu. Lẹ́yìn náà ó lọ sí Antioku. Ó dúró níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. Ó bá tún kúrò, ó la agbègbè Galatia ati ti Firigia já, ó ń mú gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu lọ́kàn le. Ọkunrin Juu kan, ará Alẹkisandria, dé sí Efesu. Orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Apolo. Ọ̀rọ̀ dùn lẹ́nu rẹ̀, ó sì mọ Ìwé Mímọ́ pupọ. A ti fi ọ̀nà Oluwa kọ́ ọ, a máa sọ̀rọ̀ pẹlu ìtara; a sì máa kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ nípa Jesu ní àkọ́yé. Ṣugbọn ìrìbọmi tí Johanu ṣe nìkan ni ó mọ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ pẹlu ìgboyà ninu ilé ìpàdé àwọn Juu. Nígbà tí Pirisila ati Akuila gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n mú un, wọ́n túbọ̀ fi ọ̀nà Ọlọrun yé e yékéyéké. Nígbà tí ó fẹ́ kọjá lọ sí Akaya, àwọn onigbagbọ ní Efesu fún un ní ìwúrí, wọ́n kọ ìwé sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ní Akaya pé kí wọ́n gbà á tọwọ́-tẹsẹ̀. Nígbà tí Apolo dé Akaya, ó wúlò lọpọlọpọ fún àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ nípa oore-ọ̀fẹ́ níbẹ̀. Bí ó bá bá àwọn Juu jiyàn níwájú gbogbo àwùjọ, a máa borí wọn, kedere ni ó ń fihàn láti inú Ìwé Mímọ́ pé Jesu ni Mesaya. Nígbà tí Apolo wà ní Kọrinti, Paulu gba ọ̀nà ilẹ̀ la àwọn ìlú tí ó wà ní àríwá Antioku kọjá títí ó fi dé Efesu. Ó rí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu mélòó kan níbẹ̀. Ó bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ gba Ẹ̀mí Mímọ́ nígbà tí ẹ gba Jesu gbọ́?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Rárá o! A kò tilẹ̀ gbọ́ ọ rí pé nǹkankan wà tí ń jẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́.” Paulu tún bi wọ́n pé, “Ìrìbọmi ti ta ni ẹ ṣe?” Wọ́n ní, “Ìrìbọmi ti Johanu ni.” Paulu bá sọ pé, “Ìrìbọmi pé a ronupiwada ni Johanu ṣe. Ó ń sọ fún àwọn eniyan pé kí wọ́n gba ẹni tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn òun gbọ́. Ẹni náà ni Jesu.” Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n gbà fún Paulu, ó sì rì wọ́n bọmi lórúkọ Oluwa Jesu. Nígbà tí Paulu gbé ọwọ́ lé wọn, Ẹ̀mí Mímọ́ bà lé wọn, wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí fi èdè mìíràn sọ̀rọ̀, wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀. Gbogbo àwọn ọkunrin náà tó mejila. Paulu wọ inú ilé ìpàdé lọ. Fún oṣù mẹta ni ó fi ń sọ̀rọ̀ pẹlu ìgboyà; ó ń fi ọ̀rọ̀ yé àwọn eniyan nípa ìjọba Ọlọrun, ó ń gbìyànjú láti yí wọn lọ́kàn pada. Ṣugbọn nígbà tí àwọn kan ṣe agídí, tí wọn kò gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́, tí wọn ń sọ̀rọ̀ burúkú sí ọ̀nà Oluwa níwájú gbogbo àwùjọ, Paulu yẹra kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó kó àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu lọ sí gbọ̀ngàn Tirani, ó sì ń bá wọn sọ̀rọ̀ níbẹ̀ lojoojumọ. Báyìí ló ṣe fún ọdún meji, tí ó fi jẹ́ pé gbogbo àwọn tí ń gbé Esia: ati Juu ati Giriki, ni ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Oluwa. Ọlọrun fún Paulu lágbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn eniyan fi ń mú ìdikù tabi aṣọ-iṣẹ́ tí ó ti kan ara Paulu, lọ fi lé àwọn aláìsàn lára, àìsàn wọn sì ń fi wọ́n sílẹ̀, ẹ̀mí burúkú sì ń jáde kúrò lára wọn. Àwọn Juu kan tí wọ́n ti ń kiri láti ìlú dé ìlú, tí wọn ń lé ẹ̀mí burúkú jáde kúrò ninu àwọn eniyan, fẹ́ máa ṣe bíi Paulu nípa pípe orúkọ Oluwa Jesu lé àwọn tí ó ní ẹ̀mí burúkú lórí. Wọ́n á máa wí pé, “Mo pàṣẹ fun yín lórúkọ Jesu tí Paulu ń ròyìn nípa rẹ̀.” Àwọn Juu meje kan tí wọn jẹ́ ọmọ Sikefa Olórí Alufaa wà, tí wọn ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹni tí ẹ̀mí burúkú wà ninu rẹ̀ bá bi wọ́n pé, “Mo mọ Jesu; mo sì mọ Paulu. Tiyín ti jẹ́?” Ni ọkunrin tí ẹ̀mí burúkú wà ninu rẹ̀ bá fò mọ́ wọn; ó gbé ìjà ńlá kò wọ́n, ó sì ṣẹgun gbogbo wọn, ó ṣe wọ́n léṣe tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi sá jáde ninu ilé náà ní ìhòòhò, tàwọn ti ọgbẹ́ lára. Gbogbo àwọn Juu ati àwọn Giriki tí ó ń gbé Efesu ni wọ́n gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ yìí. Ẹ̀rù ba gbogbo wọn; wọ́n sì gbé orúkọ Jesu Oluwa ga. Pupọ ninu àwọn onigbagbọ ni wọ́n jẹ́wọ́ ohun tí wọ́n ti ṣe, tí wọ́n tún tú àṣírí idán tí wọn ń pa. Àwọn mélòó kan ninu àwọn oníṣẹ́ òkùnkùn kó ìwé idán wọn jọ, wọ́n bá dáná sun wọ́n lójú gbogbo eniyan. Nígbà tí wọ́n ṣírò iye owó àwọn ìwé ọ̀hún, wọ́n rí i pé ó tó ọ̀kẹ́ meji ààbọ̀ (50,000) owó fadaka. Báyìí ni ọ̀rọ̀ Oluwa fi agbára hàn; ó ń tàn kálẹ̀, ó sì ń lágbára. Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọnyi, Paulu pinnu lọ́kàn rẹ̀ láti gba Masedonia lọ sí Akaya, kí ó wá ti ibẹ̀ lọ sí Jerusalẹmu. Ó ní, “Nígbà tí mo bá dé ibẹ̀, ó yẹ kí n fojú ba Romu náà.” Ó bá rán àwọn meji ninu àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀, Timoti ati Erastu, lọ sí Masedonia ṣugbọn òun alára dúró fún ìgbà díẹ̀ sí i ní Esia. Ní àkókò náà, rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀, tí kì í ṣe kékeré, nípa ọ̀nà Oluwa. Ọkunrin kan wà tí ń jẹ́ Demeteriu, alágbẹ̀dẹ fadaka. A máa fi fadaka ṣe ilé ìsìn ti oriṣa Atẹmisi; èyí a sì máa mú èrè pupọ wá fún àwọn tí ń ṣe iṣẹ́ ọnà yìí. Demeteriu wá pe àpèjọ àwọn alágbẹ̀dẹ fadaka ati àwọn tí iṣẹ́ wọn fara jọra. Ó ní, “Ẹ̀yin eniyan wa, ẹ mọ̀ pé ninu iṣẹ́ yìí ni a ti ń rí èrè wa. Ẹ wá rí i, ẹ tún ti gbọ́ pé kì í ṣe ní Efesu nìkan ni, ṣugbọn ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé ní gbogbo Esia ni Paulu yìí ti ń yí ọ̀pọ̀ eniyan lọ́kàn pada. Ó ní àwọn ohun tí a fọwọ́ ṣe kì í ṣe oriṣa! Ewu wà fún wa pé, iṣẹ́ wa yóo di ohun tí eniyan kò ní kà sí mọ́. Ṣugbọn èyí nìkan kọ́, ewu tí ó tún wà ni pé, ilé ìsìn oriṣa ńlá wa, Atẹmisi, yóo di ohun tí ẹnikẹ́ni kò ní ṣújá mọ́. Láìpẹ́ kò sí ẹni tí yóo gbà pé oriṣa wa tóbi mọ́, oriṣa tí gbogbo Esia ati gbogbo àgbáyé ń sìn!” Nígbà tí wọ́n gbọ́, inú bí wọn pupọ. Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí kígbe, wọ́n ń wí pé, “Oriṣa ńlá ni Atẹmisi, oriṣa àwọn ará Efesu!” Ni gbogbo ìlú bá dàrú. Wọ́n mú Gaiyu ati Arisitakọsi ará Masedonia, àwọn ẹlẹgbẹ́ Paulu ninu ìrìn àjò rẹ̀, gbogbo wọn bá rọ́ lọ sí ilé-ìṣeré. Paulu fẹ́ wọ ibẹ̀ lọ bá àwọn èrò ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu kò gbà fún un. Àwọn ọ̀rẹ́ Paulu kan tí wọ́n jẹ́ ìjòyè ní agbègbè Esia ranṣẹ lọ bẹ̀ ẹ́ pé kí ó má yọjú sí ilé-ìṣeré nítorí gbogbo àwùjọ ti dàrú. Bí àwọn kan ti ń kígbe bákan, bẹ́ẹ̀ ni àwọn mìíràn ń kígbe bá mìíràn. Ọpọlọpọ kò tilẹ̀ mọ ìdí rẹ̀ tí wọ́n fi péjọ! Àwọn mìíràn rò pé Alẹkisanderu ni ó dá gbogbo rẹ̀ sílẹ̀, nítorí òun ni àwọn Juu tì siwaju. Alẹkisanderu fúnra rẹ̀ gbọ́wọ́ sókè, ó fẹ́ bá àwọn èrò sọ̀rọ̀. Nígbà tí wọ́n mọ̀ pé Juu ni, wọ́n figbe ta, wọ́n ń pariwo fún ìwọ̀n wakati meji. Wọ́n ń kígbe pé, “Oriṣa ńlá ni Atẹmisi, oriṣa àwọn ará Efesu!” Akọ̀wé ìgbìmọ̀ ìlú ló mú kí wọ́n dákẹ́. Ó wá sọ pé, “Ẹ̀yin ará Efesu, ta ni kò mọ̀ pé ìlú Efesu ni ó ń tọ́jú ilé ìsìn Atẹmisi oriṣa ńlá, ati òkúta rẹ̀ tí ó bọ́ sílẹ̀ láti ọ̀run? Kò sí ẹni tí ó lè wí pé kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Ó yẹ kí ẹ fara balẹ̀ nígbà náà; kí a má fi ìwàǹwára ṣe ohunkohun. Nítorí àwọn ọkunrin tí ẹ mú wá yìí, kò ja ilé oriṣa lólè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sọ ìsọkúsọ sí oriṣa wa. Bí Demeteriu ati àwọn oníṣẹ́ ọnà tí ó wà pẹlu rẹ̀ bá ní ẹ̀sùn kan sí ẹnikẹ́ni, kóòtù wà; àwọn gomina sì ń bẹ. Ẹ jẹ́ kí wọ́n lọ pe ara wọn lẹ́jọ́ níbẹ̀. Bí ẹ bá tún ní ọ̀rọ̀ mìíràn tí ó jù yìí lọ, a óo máa yanjú rẹ̀ ní ìgbà tí a bá ń ṣe ìpàdé. Nítorí bí a ò bá ṣọ́ra, a óo dé ilé ẹjọ́ fún ìrúkèrúdò ọjọ́ òní, kò sì sí ohun tí a lè sọ pé ó fà á bí wọ́n bá bi wá.” Lẹ́yìn tí ó ti sọ báyìí tán, ó tú àwọn eniyan náà ká. Nígbà tí rògbòdìyàn náà kásẹ̀, Paulu ranṣẹ pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu. Ó gbà wọ́n níyànjú, ó sì dágbére fún wọn, ó bá lọ sí Masedonia. Bí ó ti ń kọjá ní gbogbo agbègbè náà, bẹ́ẹ̀ ni ó ń gba àwọn eniyan níyànjú pẹlu ọ̀rọ̀ ìwúrí pupọ títí ó fi dé ilẹ̀ Giriki. Ó ṣe oṣù mẹta níbẹ̀. Bí ó ti fẹ́ máa lọ sí Siria, ó rí i pé àwọn Juu ń dìtẹ̀ sí òun, ó bá gba Masedonia pada. Sopata ọmọ Pirusi ará Beria bá a lọ. Bẹ́ẹ̀ náà ni Arisitakọsi ati Sekundu; ará Tẹsalonika ni wọ́n. Gaiyu ará Dabe ati Timoti náà bá a lọ, ati Tukikọsi ati Tirofimọsi; àwọn jẹ́ ará Esia. Àwọn tí a wí yìí ṣiwaju wa lọ, wọ́n lọ dúró dè wá ní Tiroasi. Àwa náà wá wọkọ̀ ojú omi ní Filipi lẹ́yìn Àjọ̀dún Àìwúkàrà, a bá wọn ní Tiroasi lọ́jọ́ karun-un. Ọjọ́ meje ni a lò níbẹ̀. Ní alẹ́ ọjọ́ Satide, a péjọ láti jẹun; Paulu wá ń bá àwọn onigbagbọ sọ̀rọ̀. Ó ti wà lọ́kàn rẹ̀ pé lọ́jọ́ keji ni òun óo tún gbéra. Nítorí náà ó sọ̀rọ̀ títí dòru. Àtùpà pọ̀ ninu iyàrá òkè níbi tí a péjọ sí. Ọdọmọkunrin kan tí ó ń jẹ́ Yutiku jókòó lórí fèrèsé. Ó ti sùn lọ níbi tí Paulu gbé ń sọ̀rọ̀ lọ títí. Nígbà tí oorun wọ̀ ọ́ lára, ó ré bọ́ sílẹ̀ láti orí pẹ̀tẹ́ẹ̀sì kẹta. Nígbà tí wọn óo gbé e, ó ti kú. Paulu bá sọ̀kalẹ̀, ó gbá a mú, ó dùbúlẹ̀ lé e lórí. Ó ní, “Ẹ má dààmú, nítorí ẹ̀mí rẹ̀ ṣì wà ninu rẹ̀.” Nígbà tí ó pada sókè, ó gé burẹdi, ó jẹun. Ó wá ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ títí ó fi di àfẹ̀mọ́júmọ́. Ó bá jáde lọ. Wọ́n mú ọmọ náà lọ sílé láàyè. Èyí sì tù wọ́n ninu lọpọlọpọ. A bọ́ siwaju, a wọkọ̀ ojú omi lọ sí Asọsi. Níbẹ̀ ni a lérò pé Paulu yóo ti wá bá wa tí òun náà yóo sì wọkọ̀. Òun ló ṣe ètò bẹ́ẹ̀ nítorí ó fẹ́ fẹsẹ̀ rìn dé ibẹ̀. Nígbà tí ó bá wa ní Asọsi, ó wọnú ọkọ̀ wa, a bá lọ sí Mitilene. Ní ọjọ́ keji a kúrò níbẹ̀, a dé òdìkejì erékùṣù Kiosi. Ní ọjọ́ kẹta a dé Samosi. Ní ọjọ́ kẹrin a dé Miletu. Nítorí Paulu ti pinnu láti wọkọ̀ kọjá Efesu, kí ó má baà pẹ́ pupọ ní Esia, nítorí ó ń dàníyàn pé bí ó bá ṣeéṣe, òun fẹ́ ṣe Àjọ̀dún Pẹntikọsti ní Jerusalẹmu. Láti Miletu, Paulu ranṣẹ sí Efesu kí wọ́n lọ pe àwọn alàgbà ìjọ wá. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ mọ̀ bí mo ti lo gbogbo àkókò mi láàrin yín láti ìgbà tí mo ti kọ́kọ́ dé ilẹ̀ Esia. Ẹ mọ̀ bí mo ti fi ìrẹ̀lẹ̀ ati omi ojú sin Oluwa ní ọ̀nà gbogbo ninu àwọn ìṣòro tí mo fara dà nítorí ọ̀tẹ̀ tí àwọn Juu dì sí mi. Ẹ mọ̀ pé n kò dánu dúró láti sọ ohunkohun fun yín tí yóo ṣe yín ní anfaani; mò ń kọ yín ní gbangba ati ninu ilé yín. Mò ń tẹnu mọ́ ọn fún àwọn Juu ati àwọn Giriki pé kí wọn yipada sí Ọlọrun, kí wọn ní igbagbọ ninu Oluwa Jesu. Nisinsinyii, gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí ti darí mi, mò ń lọ sí Jerusalẹmu láì mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí mi níbẹ̀, àfi pé láti ìlú dé ìlú ni Ẹ̀mí Mímọ́ ń fi àmì hàn mí pé ẹ̀wọ̀n ati ìyà ń dúró dè mí níbẹ̀. Ṣugbọn n kò ka ẹ̀mí mi sí ohunkohun tí ó ní iye lórí fún ara mi. Ohun tí mò ń lépa ni láti parí iré ìje mi ati iṣẹ́ tí mo gbà lọ́wọ́ Oluwa mi Jesu, èyí ni pé kí n tẹnu mọ́ ìyìn rere oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun. “Wàyí ò, èmi gan-an mọ̀ pé gbogbo ẹ̀yin tí mo ti ń waasu ìjọba Ọlọrun láàrin yín kò tún ní fi ojú kàn mí mọ́. Nítorí náà mo sọ fun yín lónìí yìí pé bí ẹnikẹ́ni bá ṣègbé ninu yín, ẹ̀bi mi kọ́. Nítorí n kò dánu dúró láti sọ gbogbo ohun tí Ọlọrun fẹ́ fun yín. Ẹ ṣọ́ra yín, ẹ sì ṣọ́ agbo tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi yín ṣe alabojuto lórí rẹ̀, kí ẹ máa bọ́ ìjọ Ọlọrun tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ rẹ̀ ṣe ní tirẹ̀. Mo mọ̀ pé lẹ́yìn tí mo bá lọ, àwọn ẹhànnà ìkookò yóo wọ ààrin yín; wọn kò sì ní dá agbo sí. Mo mọ̀ pé láàrin yín àwọn ẹlòmíràn yóo dìde tí wọn yóo fi irọ́ yí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu lọ́kàn pada láti tẹ̀lé wọn. Nítorí náà, ẹ máa ṣọ́ra. Ẹ ranti pé fún ọdún mẹta, tọ̀sán-tòru ni n kò fi sinmi láti máa gba ẹnìkọ̀ọ̀kan yín níyànjú pẹlu omi lójú. “Nisinsinyii, mo fi yín lé Ọlọrun lọ́wọ́ ati ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí ó lè mu yín dàgbà, tí ó sì lè fun yín ní ogún pẹlu gbogbo àwọn tí a ti sọ di mímọ́. N kò ṣe ojúkòkòrò owó tabi aṣọ tabi góòlù ẹnikẹ́ni. Ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ pé ọwọ́ ara mi yìí ni mo fi ṣiṣẹ́ tí mo fi ń gbọ́ bùkátà mi ati ti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi. Mo ti fihàn yín pé bẹ́ẹ̀ ni a níláti ṣiṣẹ́ láti ran àwọn aláìlera lọ́wọ́. Kí á máa ranti àwọn ọ̀rọ̀ Oluwa Jesu, nítorí òun fúnra rẹ̀ sọ pé, ‘Ayọ̀ pọ̀ ninu kí a máa fúnni ní nǹkan ju kí á máa gbà lọ.’ ” Nígbà tí ó sọ báyìí tán, ó kúnlẹ̀ pẹlu gbogbo wọn, ó sì gbadura. Gbogbo wọn bá ń sunkún. Wọ́n ń dì mọ́ ọn, wọ́n ń fi ẹnu kò ó lẹ́nu. Èyí tí ó dùn wọ́n jù ni ọ̀rọ̀ tí ó sọ, pé wọn kò tún ní rí ojú òun mọ́. Wọ́n bá sìn ín lọ sí ìdíkọ̀. Nígbà tí a dágbére fún wọn tán, ọkọ̀ ṣí. A wá lọ tààrà sí Kosi. Ní ọjọ́ keji a dé Rodọsi. Láti ibẹ̀ a lọ sí Patara. A rí ọkọ̀ ojú omi kan níbẹ̀ tí ó fẹ́ sọdá lọ sí Fonike. Ni a bá wọ̀ ọ́, ọkọ̀ bá ṣí. Nígbà tí à ń wo Kipru lókèèrè, a gba ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún ibẹ̀ kọjá, a bá ń bá ọkọ̀ lọ sí ilẹ̀ Siria. A gúnlẹ̀ ní ìlú Tire, nítorí níbẹ̀ ni wọ́n fẹ́ já ẹrù ọkọ̀ sí. A bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu kan níbẹ̀, a bá dúró tì wọ́n níbẹ̀ fún ọjọ́ meje. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu yìí sọ ohun tí Ẹ̀mí Mímọ́ fihàn wọ́n fún Paulu pé kí ó má lọ sí Jerusalẹmu. Nígbà tí ọjọ́ tí a óo gbé níbẹ̀ pé, a gbéra láti máa bá ìrìn àjò wa lọ. Gbogbo wọn ati àwọn iyawo wọn ati àwọn ọmọ wọn sìn wá dé ẹ̀yìn odi. A bá kúnlẹ̀ lórí iyanrìn ní èbúté, a gbadura. Ni a bá dágbére fún ara wa, a wọ inú ọkọ̀, àwọn sì pada lọ sí ilé wọn. Láti Tire, a bá ń bá ìrìn àjò wa lọ títí a fi dé Tolemaisi. Níbẹ̀ a lọ kí àwọn onigbagbọ, a sì dúró lọ́dọ̀ wọn fún ọjọ́ kan. Ní ọjọ́ keji, a gbéra, a lọ sí Kesaria. A wọ ilé Filipi, ajíyìnrere, ọ̀kan ninu àwọn meje tí àwọn ìjọ Jerusalẹmu yàn ní ijọ́sí. Lọ́dọ̀ rẹ̀ ni a dé sí. Ó ní ọmọbinrin mẹrin. Wundia ni wọ́n, wọn a sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀. A wà níbẹ̀ fún ọjọ́ pupọ. Nígbà tí à ń wí yìí ni Agabu aríran kan dé láti Judia. Nígbà tí ó wá sọ́dọ̀ wa, ó mú ọ̀já ìgbànú Paulu, ó fi de ara rẹ̀ tọwọ́-tẹsẹ̀. Ó ní, “Ẹ gbọ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti wí: Báyìí ni àwọn Juu yóo di ọkunrin tí ó ni ọ̀já ìgbànú yìí ní Jerusalẹmu; wọn yóo sì fà á lé àwọn tí kì í ṣe Juu lọ́wọ́.” Nígbà tí a gbọ́ ohun tí Agabu wí, àwa ati àwọn tí ó ń gbé ibẹ̀ bẹ Paulu pé kí ó má lọ sí Jerusalẹmu. Ṣugbọn Paulu dáhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ̀ ń sunkún, tí ẹ̀ ń mú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá mi? Mo ti múra ẹ̀wọ̀n ati ikú pàápàá ní Jerusalẹmu nítorí orúkọ Oluwa Jesu.” Nígbà tí a kò lè yí i lọ́kàn pada, a bá dákẹ́. A ní, “Ìfẹ́ Oluwa ni kí ó ṣẹ.” Lẹ́yìn tí a gbé ọjọ́ bíi mélòó kan ni Kesaria, a palẹ̀ mọ́, a bá gbọ̀nà, ó di Jerusalẹmu. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ní Kesaria bá wa lọ. Wọ́n mú wa lọ sọ́dọ̀ ẹni tí a óo dé sí ilé rẹ̀, Minasoni ará Kipru kan báyìí tí ó ti di onigbagbọ tipẹ́tipẹ́. Nígbà tí a dé Jerusalẹmu, àwọn onigbagbọ gbà wá tayọ̀tayọ̀. Ní ọjọ́ keji, Paulu bá lọ sọ́dọ̀ Jakọbu. Gbogbo àwọn àgbààgbà ni wọ́n pésẹ̀ sibẹ. Nígbà tí Paulu kí wọn tán, ó ròyìn lẹ́sẹẹsẹ iṣẹ́ tí Ọlọrun lo òun láti ṣe láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu. Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n fi ògo fún Ọlọrun. Àwọn náà wá sọ fún un pé, “Wò ó ná, arakunrin, ṣé o mọ̀ pé ẹgbẹẹgbẹrun ni àwọn Juu tí ó gba Jesu gbọ́, tí gbogbo wọn sì ní ìtara sí Òfin Mose. Wọ́n ń sọ nípa rẹ pé ò ń kọ́ gbogbo àwọn Juu tí ń gbé ààrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn pé kí wọ́n yapa kúrò ninu ìlànà Mose. Wọ́n ní o sọ pé kí wọn má kọ ọmọ wọn nílà; àtipé kí wọn má tẹ̀lé àṣà ìbílẹ̀ wọn mọ́. Èwo ni ṣíṣe? Ó dájú pé wọn á gbọ́ pé o ti dé. Bí a bá ti wí fún ọ ni kí o ṣe. Àwọn ọkunrin mẹrin kan wà lọ́dọ̀ wa tí wọ́n ti jẹ́jẹ̀ẹ́. Mú wọn, kí o lọ bá wọn wẹ ẹ̀jẹ́ náà kúrò. San gbogbo owó tí wọn óo bá ná ati tìrẹ náà. Kí wọn wá fá orí wọn. Èyí yóo jẹ́ kí gbogbo eniyan mọ̀ pé kò sí òótọ́ ninu gbogbo nǹkan tí wọn ń sọ nípa rẹ. Wọn yóo mọ̀ pé Juu hánún-hánún ni ọ́ àtipé ò ń pa Òfin Mose mọ́. Ní ti àwọn tí kì í ṣe Juu tí wọ́n gba Jesu gbọ́, a ti kọ ìwé sí wọn pé kí wọ́n yẹra fún oúnjẹ tí a ti fi rúbọ sí oriṣa, ati ẹ̀jẹ̀, ati ẹran tí a lọ́ lọ́rùn pa; kí wọn sì ṣọ́ra fún àgbèrè.” Ní ọjọ́ keji, Paulu mú àwọn ọkunrin náà, ó ṣe ètò láti wẹ ẹ̀jẹ́ wọn kúrò, ati tirẹ̀ pẹlu. Ó wọ Tẹmpili lọ láti lọ ṣe ìfilọ̀ ọjọ́ tí àkókò ìwẹ̀nùmọ́ wọn yóo parí, tí òun yóo mú ọrẹ ti ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn wá. Nígbà tí ọjọ́ meje náà fẹ́rẹ̀ pé, àwọn Juu láti Esia rí Paulu ninu Tẹmpili. Wọ́n bá ké ìbòòsí láàrin gbogbo èrò, wọ́n sì dọwọ́ bo Paulu, wọ́n ń kígbe pé, “Ẹ̀yin eniyan Israẹli, ẹ gbani o! Ọkunrin tí ń kọ́ àwọn eniyan nígbà gbogbo láti lòdì sí orílẹ̀-èdè wa ati Òfin Mose ati ilé yìí nìyí. Ó tún mú àwọn Giriki wọ inú Tẹmpili; ó wá sọ ibi mímọ́ yìí di àìmọ́.” Wọ́n sọ báyìí nítorí pé wọ́n ti kọ́kọ́ rí Tirofimọsi ará Efesu pẹlu Paulu láàrin ìlú, wọ́n wá ṣebí Paulu mú un wọ inú Tẹmpili ni. Gbogbo ìlú bá dàrú. Àwọn eniyan ń rọ́ lọ sọ́dọ̀ Paulu. Wọ́n bá mú un, wọ́n wọ́ ọ jáde kúrò ninu Tẹmpili. Lẹsẹkẹsẹ wọ́n bá ti gbogbo ìlẹ̀kùn. Wọ́n fẹ́ pa á ni ìròyìn bá kan ọ̀gá àwọn ọmọ-ogun pé gbogbo Jerusalẹmu ti dàrú. Lójú kan náà ó bá mú àwọn ọmọ-ogun pẹlu àwọn balogun ọ̀rún tí ó wà lábẹ́ rẹ̀, ó sáré lọ bá wọn. Nígbà tí àwọn èrò rí ọ̀gágun ati àwọn ọmọ-ogun, wọ́n dáwọ́ dúró, wọn kò lu Paulu mọ́. Ọ̀gágun bá súnmọ́ Paulu, ó mú un, ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n fi ẹ̀wọ̀n meji dè é. Ó wá wádìí ẹni tí ó jẹ́ ati ohun tí ó ṣe. Àwọn kan ninu èrò ń sọ nǹkankan; àwọn mìíràn ń sọ nǹkan mìíràn. Nígbà tí ọ̀gágun náà kò lè mọ òtítọ́ ọ̀rọ̀ náà nítorí ariwo èrò, ó pàṣẹ pé kí wọ́n mú Paulu lọ sí àgọ́ àwọn ọmọ-ogun. Nígbà tí wọ́n dé àtẹ̀gùn ilé, gbígbé ni àwọn ọmọ-ogun níláti gbé Paulu wọlé nítorí ojú àwọn èrò ti ranko. Ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan ni wọ́n ń tẹ̀lé wọn, tí wọn ń kígbe pé, “Ẹ pa á!” Bí wọ́n ti fẹ́ mú Paulu wọ inú àgọ́ ọmọ-ogun, ó sọ fún ọ̀gágun pé, “Ṣé kò léèwọ̀ bí mo bá bá ọ sọ nǹkankan?” Ọ̀gágun wá bi í léèrè pé, “O gbọ́ èdè Giriki? Ìyẹn ni pé kì í ṣe ìwọ ni ará Ijipti tí ó dá rúkèrúdò sílẹ̀ láìpẹ́ yìí, tí ó kó ẹgbaaji (4000) àwọn agúnbẹ lẹ́yìn lọ sí aṣálẹ̀?” Paulu dáhùn ó ní, “Juu ni mí, ará Tasu ní ilẹ̀ Silisia. Ọmọ ìlú tí ó lókìkí ni mí. Gbà mí láàyè kí n bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀.” Nígbà tí ó gbà fún un, Paulu dúró lórí àtẹ̀gùn, ó gbọ́wọ́ sókè kí àwọn eniyan lè dákẹ́. Nígbà tí wọ́n dákẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ ní èdè àwọn Heberu. Ó ní “Ẹ̀yin ará mi ati ẹ̀yin baba wa, ẹ fetí sí ẹjọ́ tí mo ní í rò fun yín nisinsinyii.” Nígbà tí wọ́n gbọ́ tí ó ń bá wọn sọ̀rọ̀ ní èdè Heberu, wọ́n pa lọ́lọ́. Paulu bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, ó ní, “Juu ni mí, Tasu ní ilẹ̀ Silisia la gbé bí mi. Ní ìlú yìí ni a gbé tọ́ mi dàgbà. Ilé-ìwé Gamalieli ni mo lọ, ó sì kọ́ mi dáradára nípa Òfin ìbílẹ̀ wa. Mo ní ìtara fún Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí gbogbo yín ti ní lónìí. Mo ṣe inúnibíni sí ọ̀nà ẹ̀sìn yìí. Gbogbo àwọn tí ń tẹ̀lé Jesu ni mò ń lé kiri: ẹni tí mo bá sì bá ninu wọn pípa ni. Èmi a mú wọn, èmi a dè wọ́n, wọn a sì sọ wọ́n sẹ́wọ̀n, atọkunrin atobinrin wọn. Olórí Alufaa pàápàá lè jẹ́rìí mi, ati gbogbo àwọn àgbààgbà. Ọwọ́ wọn ni mo ti gba ìwé lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arakunrin wa ní Damasku. Mo lọ sibẹ láti de àwọn ẹlẹ́sìn yìí kí n sì mú wọn wá sí Jerusalẹmu láti jẹ wọ́n níyà. “Bí mo ti ń lọ, tí mo súnmọ́ Damasku, lójijì, ní ọ̀sán gangan, ìmọ́lẹ̀ ńlá kan láti ọ̀run tàn yí mi ká. Mo bá ṣubú lulẹ̀. Mo wá gbọ́ ohùn ẹnìkan tí ó ń sọ fún mi pé, ‘Saulu! Saulu! Kí ló dé tí o fi ń ṣe inúnibíni sí mi?’ Mo wá dáhùn, mo ní, ‘Ta ni ọ́, Oluwa?’ Ó bá sọ fún mi pé, ‘Èmi ni Jesu ará Nasarẹti, ẹni tí ò ń ṣe inúnibíni sí.’ Àwọn tí wọ́n wà pẹlu mi rí ìmọ́lẹ̀ náà, ṣugbọn wọn kò gbọ́ ohùn ẹni tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀. Mo bá bèèrè pé, ‘Kí ni kí n ṣe Oluwa?’ Oluwa bá dá mi lóhùn pé, ‘Dìde kí o máa lọ sí Damasku. Níbẹ̀ a óo sọ fún ọ gbogbo nǹkan tí a ti ṣètò fún ọ láti ṣe.’ N kò lè ríran mọ́ nítorí ìmọ́lẹ̀ náà mọ́lẹ̀ pupọ. Àwọn ẹni tí ó wà pẹlu mi bá fà mí lọ́wọ́ lọ sí Damasku. “Lẹ́yìn náà ni ọkunrin kan tí ń jẹ́ Anania dé. Ó jẹ́ olùfọkànsìn nípa ti Òfin Mose; gbogbo àwọn ẹni tí ń gbé Judia ni wọ́n sì jẹ́rìí rere nípa rẹ̀. Ó dúró tì mí, ó ní, ‘Saulu arakunrin, lajú!’ Lẹsẹkẹsẹ ojú mi là, mo bá gbójú sókè wò ó. Ó bá sọ fún mi pé, Ọlọrun àwọn baba wa ni ó yàn mí tẹ́lẹ̀ pé kí n mọ ìfẹ́ rẹ̀, kí n fojú rí iranṣẹ Olódodo rẹ̀, kí n sì gbọ́ ohùn òun pàápàá; kí n lè ṣe ẹlẹ́rìí rẹ̀ níwájú gbogbo eniyan nípa ohun tí mo rí, ati ohun tí mo gbọ́. Ó wá bèèrè pé, kí ni mo tún ń fẹ́ nisinsinyii? Ó ní kí n dìde, kí n ṣe ìrìbọmi, kí n wẹ ẹ̀ṣẹ̀ mi nù, kí n pe orúkọ Oluwa. “Nígbà tí mo ti pada sí Jerusalẹmu, bí mo ti ń gbadura ninu Tẹmpili, mo rí ìran kan. Mo rí Oluwa tí ó ń sọ fún mi pé, ‘Jáde kúrò ní Jerusalẹmu kíákíá, nítorí wọn kò ní gba ẹ̀rí tí ò ń jẹ́ nípa mi.’ Mo dáhùn, mo ní, ‘Oluwa, àwọn gan-an mọ̀ pé èmi ni mo máa ń sọ àwọn tí ó bá gbà ọ́ gbọ́ sẹ́wọ̀n, tí mo sì máa ń nà wọ́n káàkiri láti ilé ìpàdé kan dé ekeji. Wọ́n mọ̀ pé nígbà tí wọ́n pa Stefanu, ẹlẹ́rìí rẹ, bí mo ti dúró nìyí, tí mò ń kan sáárá sí àwọn tí ó pa á tí mò ń ṣọ́ aṣọ wọn.’ Ṣugbọn Oluwa sọ fún mi pé, ‘Bọ́ sọ́nà, nítorí n óo rán ọ lọ sí ọ̀nà jíjìn, sí ọ̀dọ̀ àwọn tí kì í ṣe Juu.’ ” Àwọn eniyan fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ títí gbolohun yìí fi jáde. Nígbà tí wọ́n gbọ́ gbolohun yìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pé, “Ẹ pa irú ẹni bẹ́ẹ̀ rẹ́ kúrò láyé! Kò yẹ kí ó wà láàyè!” Wọ́n bá ń pariwo, wọ́n ń fi aṣọ wọn, wọ́n sì ń da ìyẹ̀pẹ̀ sókè. Ni ọ̀gágun bá pàṣẹ pé kí wọ́n mú Paulu wọ àgọ́ ọmọ-ogun lọ. Ó ní kí wọn nà án kí wọn fi wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀, kí ó lè mọ ìdí tí àwọn eniyan ṣe ń pariwo lé e lórí bẹ́ẹ̀. Bí wọ́n ti ń dè é mọ́lẹ̀ láti máa nà án, Paulu bi balogun ọ̀rún tí ó dúró pé, “Ẹ̀tọ́ wo ni ẹ níláti na ọmọ-ìbílẹ̀ Romu láì tíì dá a lẹ́jọ́?” Nígbà tí balogun ọ̀rún gbọ́, ó lọ sọ́dọ̀ ọ̀gágun, ó bi í pé, “Kí lẹ fẹ́ ṣe? Ọmọ ìbílẹ̀ Romu ni ọkunrin yìí o!” Ní ọ̀gágun bá lọ bi Paulu, ó ní, “Wí kí n gbọ́, ọmọ-ìbílẹ̀ Romu ni ọ́?” Paulu dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.” Ọ̀gágun náà bá dá a lóhùn pé, “Ọpọlọpọ owó ni mo ná kí n tó di ọmọ-ìbílẹ̀ Romu.” Ṣugbọn Paulu ní, “Ní tèmi o, wọ́n bí mi bẹ́ẹ̀ ni.” Lẹsẹkẹsẹ ni àwọn tí wọ́n fẹ́ wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀ bá bìlà. Ẹ̀rù wá ba ọ̀gágun náà nígbà tí ó mọ̀ pé ọmọ-ìbílẹ̀ Romu ni Paulu, àtipé òun ti fi ẹ̀wọ̀n dè é. Lọ́jọ́ keji, ọ̀gágun náà tú Paulu sílẹ̀. Ó fẹ́ mọ òtítọ́ ẹ̀sùn tí àwọn Juu mú wá nípa rẹ̀. Ó bá pàṣẹ pé kí àwọn olórí alufaa ati gbogbo ìgbìmọ̀ péjọ. Ó bá mú Paulu lọ siwaju wọn. Paulu kọjú sí àwọn ìgbìmọ̀, ó ní, “Ẹ̀yin ará, ní gbogbo ìgbé-ayé mi, ọkàn mí mọ́ níwájú Ọlọrun títí di òní.” Bí ó ti sọ báyìí, bẹ́ẹ̀ ni Anania Olórí Alufaa sọ fún àwọn tí ó dúró ti Paulu pé kí wọ́n gbá a lẹ́nu. Paulu wá sọ fún un pé, “Ọlọrun yóo lù ọ́. Ìwọ ògiri tí wọ́n kùn lẹ́fun lásán yìí! O jókòó sibẹ, ò ń dá mi lẹ́jọ́ lórí Òfin, sibẹ o pa Òfin tì, o ní kí wọ́n lù mí.” Àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀ bá ní, “Olórí Alufaa Ọlọrun ni ò ń bú bẹ́ẹ̀?” Paulu dáhùn pé, “Ará, n kò mọ̀ pé Olórí Alufaa ni. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ burúkú sí aláṣẹ àwọn eniyan rẹ.’ ” Nígbà tí Paulu mọ̀ pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Sadusi ni apá kan ninu àwọn tí wọ́n wà ninu ìgbìmọ̀, àtipé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Farisi ni àwọn mìíràn, ó kígbe pé, “Ẹ̀yin ará, Farisi ni mí. Farisi ni àwọn òbí mi. Nítorí ìrètí wa pé àwọn òkú yóo jí dìde ni wọ́n ṣe mú mi wá dáhùn ẹjọ́.” Nígbà tí ó sọ báyìí, ìyapa bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn Farisi ati àwọn Sadusi, ìgbìmọ̀ bá pín sí meji. Nítorí àwọn Sadusi sọ pé kò sí ajinde, bẹ́ẹ̀ ni kò sí angẹli tabi àwọn ẹ̀mí; ṣugbọn àwọn Farisi gbà pé mẹtẹẹta wà. Ni ariwo ńlá bá bẹ́ sílẹ̀. Àwọn amòfin kan ninu àwọn Farisi dìde, wọ́n tẹnu mọ́ ọn pé, “Àwa kò rí nǹkan burúkú tí ọkunrin yìí ṣe. Bí ó bá jẹ́ pé ẹ̀mí ni ó sọ̀rọ̀ fún un ńkọ́? Tabi angẹli?” Nígbà tí àríyànjiyàn náà pọ̀ pupọ, ẹ̀rù ba ọ̀gágun pé kí wọn má baà fa Paulu ya. Ó bá pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ogun kí wọn wá fi agbára mú Paulu kúrò láàrin wọn, kí wọn mú un wọnú àgọ́ àwọn ọmọ-ogun lọ. Ní òru ọjọ́ keji, Oluwa dúró lẹ́bàá Paulu, ó ní, “Ṣe ọkàn rẹ gírí. Gẹ́gẹ́ bí o ti jẹ́rìí iṣẹ́ mi ní Jerusalẹmu, bẹ́ẹ̀ ni o níláti jẹ́rìí nípa mi ní Romu náà.” Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn Juu péjọ pọ̀ láti dìtẹ̀ sí Paulu. Wọ́n búra pé àwọn kò ní jẹun, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kò ní mu omi títí àwọn yóo fi pa Paulu. Àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ yìí ju bí ogoji lọ. Wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbààgbà, wọ́n ní, “A ti jẹ́jẹ̀ẹ́, a sì ti búra pé a kò ní fẹnu kan nǹkankan títí a óo fi pa Paulu. A fẹ́ kí ẹ̀yin ati gbogbo wa ranṣẹ sí ọ̀gá àwọn ọmọ-ogun pé kí ó fi Paulu ranṣẹ sí yín nítorí ẹ fẹ́ wádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ fínnífínní. Ní tiwa, a óo ti múra sílẹ̀ láti pa á kí ó tó dé ọ̀dọ̀ yín.” Ṣugbọn ọmọ arabinrin Paulu kan gbọ́ nípa ète yìí. Ó bá lọ sí àgọ́ àwọn ọmọ-ogun, ó lọ ròyìn fún Paulu. Paulu wá pe ọ̀kan ninu àwọn balogun ọ̀rún, ó ní, “Mú ọdọmọkunrin yìí lọ sọ́dọ̀ ọ̀gágun, nítorí ó ní ọ̀rọ̀ kan láti sọ fún un.” Balogun ọ̀rún náà bá mú un lọ sọ́dọ̀ ọ̀gágun. Ó ní, “Ẹlẹ́wọ̀n tí ń jẹ́ Paulu ni ó pè mí, tí ó ní kí n mú ọdọmọkunrin yìí wá sọ́dọ̀ yín nítorí ó ní ọ̀rọ̀ kan láti sọ fun yín.” Ọ̀gágun náà bá fà á lọ́wọ́, ó mú un lọ sí kọ̀rọ̀. Ó wá bi í pé, “Kí ni o ní sọ fún mi?” Ọdọmọkunrin náà wá dáhùn pé, “Àwọn Juu ti fohùn ṣọ̀kan láti bẹ̀ yín pé kí ẹ mú Paulu wá siwaju ìgbìmọ̀ lọ́la kí àwọn le wádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní fínnífínní. Ẹ má gbà fún wọn. Nítorí àwọn kan ninu wọn yóo dènà dè é, wọ́n ju ogoji lọ. Wọ́n ti búra pé àwọn kò ní jẹun, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kò ní mu omi títí àwọn yóo fi pa Paulu. Bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí, wọ́n ti múra tán. Ohun tí wọn ń retí ni kí ẹ ṣe ìlérí pé ẹ óo fi Paulu ranṣẹ sí ìgbìmọ̀.” Ọ̀gágun bá ní kí ọdọmọkunrin náà máa lọ. Ó kìlọ̀ fún un pé kí ó má sọ fún ẹnikẹ́ni pé ó ti fi ọ̀rọ̀ yìí tó òun létí. Ọ̀gágun náà bá pe meji ninu àwọn balogun ọ̀rún tí ó wà lábẹ́ rẹ̀, ó ní, “Ẹ lọ mú igba ọmọ-ogun ati aadọrin ẹlẹ́ṣin ati igba ọmọ-ogun tí ó ní ọ̀kọ̀. Ẹ óo lọ sí Kesaria. Kí ẹ múra láti lọ ní agogo mẹsan-an alẹ́. Ẹ tọ́jú àwọn ẹṣin tí Paulu yóo gùn, kí ẹ sìn ín dé ọ̀dọ̀ Fẹliksi gomina ní alaafia.” Ó wá kọ ìwé lé wọn lọ́wọ́. Ìwé náà lọ báyìí: “Gomina ọlọ́lá jùlọ, Fẹliksi, èmi Kilaudiu Lisia ki yín. Àwọn Juu mú ọkunrin yìí, wọ́n fẹ́ pa á. Mo gbà á lọ́wọ́ wọn pẹlu àwọn ọmọ-ogun mi nítorí mo gbọ́ pé ọmọ-ìbílẹ̀ Romu ni. Mo fẹ́ mọ ìdí tí wọ́n ṣe fi ẹ̀sùn kàn án. Mo bá mú un lọ sí iwájú ìgbìmọ̀ wọn. Mo rí i pé ẹ̀sùn tí wọ́n ní jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ òfin wọn; kò ṣe ohunkohun tí a lè fi sọ pé kí á pa á tabi kí á jù ú sí ẹ̀wọ̀n. Nígbà tí ìròyìn kàn mí pé àwọn kan láàrin àwọn Juu ti dìtẹ̀ sí ọkunrin yìí, mo bá fi í ranṣẹ si yín. Mo ti sọ fún àwọn tí ó fi ẹ̀sùn kàn án pé kí wọ́n wá sọ ohun tí wọ́n ní sí i níwájú yín.” Àwọn ọmọ-ogun ṣe bí a ti pàṣẹ fún wọn. Wọ́n mú Paulu lóru lọ sí ìlú Antipatiri. Ní ọjọ́ keji wọ́n fi Paulu sílẹ̀ pẹlu àwọn ọmọ-ogun ẹlẹ́ṣin, wọ́n pada sí àgọ́ wọn. Àwọn ọmọ-ogun ẹlẹ́ṣin bá a lọ sí Kesaria. Wọ́n fún gomina ní ìwé, wọ́n sì fa Paulu lé e lọ́wọ́. Gomina ka ìwé náà. Ó wá wádìí pé apá ibo ni Paulu ti wá. Wọ́n sọ fún un pé ní agbègbè Silisia ni. Ó bá sọ fún un pé, “N óo gbọ́ ẹjọ́ rẹ nígbà tí àwọn tí ó fi ẹjọ́ rẹ sùn náà bá dé.” Ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n máa ṣọ́ Paulu ní ààfin Hẹrọdu. Lẹ́yìn ọjọ́ marun-un, Anania olórí Alufaa dé pẹlu àwọn àgbààgbà ati agbẹjọ́rò kan tí ń jẹ́ Tatulu. Wọ́n ro ẹjọ́ Paulu fún gomina. Nígbà tí wọ́n pe Paulu, Tatulu bẹ̀rẹ̀ sí rojọ́. Ó ní: “Fẹliksi ọlọ́lá jùlọ, à ń jọlá alaafia tí ẹ mú wá lọpọlọpọ, a sì ń gbádùn oríṣìíríṣìí àtúnṣe tí ẹ̀ ń ṣe lọ́tùn-ún lósì fún àwọn ọmọ ilẹ̀ wa. Ọjọ́ iwájú ni ẹ̀ ń rò tí ẹ fi ń ṣe èyí nígbà gbogbo. A dúpẹ́ pupọ lọ́wọ́ yín. N kò fẹ́ gbà yín ní àkókò títí, mo bẹ̀ yín kí ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ gbọ́ ohun tí a níláti sọ ní ṣókí. Onijamba eniyan ni ọkunrin yìí; rúkèrúdò ni ó ń dá sílẹ̀ láàrin àwọn Juu ní gbogbo àgbáyé. Ọ̀gá ni ninu ẹgbẹ́ àwọn Nasarene. A ká a mọ́ ibi tí ó ti fẹ́ mú ohun ẹ̀gbin wọ inú Tẹmpili, a bá mú un. [A fẹ́ jẹ ẹ́ níyà gẹ́gẹ́ bí òfin wa. Ṣugbọn ọ̀gágun Lisia wá fi ipá gbà á kúrò lọ́wọ́ wa, ni ó bá mú un lọ. Òun ni ó pàṣẹ pé kí àwọn tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn án wá siwaju yín.] Bí ẹ bá wádìí lẹ́nu òun fúnrarẹ̀, ẹ óo rí i pé òtítọ́ ni gbogbo ẹjọ́ rẹ̀ tí a fi sùn yín.” Àwọn Juu náà gbè é lẹ́sẹ̀; wọ́n ní bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó sọ rí. Gomina wá mi orí sí Paulu. Paulu wá bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ tirẹ̀. Ó ní: “Ó dùn mọ́ mi pé níwájú yín ni n óo ti sọ ti ẹnu mi. Nítorí mo mọ̀ pé ẹ ti ń ṣe onídàájọ́ ní orílẹ̀-èdè wa yìí fún ọpọlọpọ ọdún. Kò ju ọjọ́ mejila lọ nisinsinyii tí mo lọ ṣọdún ní Jerusalẹmu. Ẹ lè wádìí èyí. Ẹnìkan kò rí mi kí n máa bá ẹnikẹ́ni jiyàn ninu Tẹmpili. Bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kò rí mi pé mo kó àwọn eniyan jọ láti dá rúkèrúdò sílẹ̀, ìbáà ṣe ninu ilé ìpàdé ni tabi níbikíbi láàrin ìlú. Wọn kò lè rí ohunkohun wí tí ẹ lè rí dìmú ninu ẹjọ́ tí wọn wá ń rò mọ́ mi lẹ́sẹ̀ nisinsinyii. Ṣugbọn mo jẹ́wọ́ ohun kan fun yín: lóòótọ́ ni mò ń sin Ọlọrun àwọn baba wa ní ọ̀nà tí ó yàtọ̀. Mo gba gbogbo ohun tí ó wà ninu ìwé Òfin ati ninu ìwé àwọn wolii. Mo sì ń wojú Ọlọrun nítorí pé mo ní ìrètí kan náà tí àwọn ará ibí yìí pàápàá tí wọn ń rojọ́ mi ní, pé gbogbo òkú ni yóo jinde, ati ẹni rere ati ẹni burúkú. Ìdí nìyí tí mo fi ń sa ipá mi kí ọkàn mi lè jẹ́ mi lẹ́rìí pé inú mi mọ́ sí Ọlọrun ati eniyan nígbà gbogbo. “Ó ti tó ọdún mélòó kan tí mo ti dé Jerusalẹmu gbẹ̀yìn. Ìtọrẹ àánú ni mo mú wá fún àwọn orílẹ̀-èdè mi, kí n sì rúbọ. Níbi tí mo gbé ń ṣe èyí, wọ́n rí mi ninu Tẹmpili. Mo ti wẹ ara mi mọ́ nígbà náà. N kò kó èrò lẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ ni n kò fa ìjàngbọ̀n. Ṣugbọn àwọn Juu kan láti Esia wà níbẹ̀. Àwọn ni ó yẹ kí wọ́n wá siwaju yín bí wọn bá ní ẹ̀sùn kan sí mi. Tabi, kí àwọn tí wọ́n wà níhìn-ín fúnra wọn sọ nǹkan burúkú kan tí wọ́n rí pé mo ṣe nígbà tí mo wà níwájú ìgbìmọ̀. Àfi gbolohun kan tí mo sọ nígbà tí mo dúró láàrin wọn, pé, ‘Ìdí tí a fi mú mi wá fún ìdájọ́ níwájú yín lónìí ni pé mo ní igbagbọ pé àwọn òkú yóo jinde.’ ” Fẹliksi bá sún ọjọ́ ìdájọ́ siwaju. Ó mọ ohun tí ọ̀nà igbagbọ jẹ́ dáradára. Ó ní, “Nígbà tí ọ̀gágun Lisia bá dé, n óo sọ bí ọ̀rọ̀ yín ti rí lójú mi.” Ó bá pàṣẹ fún balogun ọ̀rún pé kí ó máa ṣọ́ Paulu. Ó ní kí ó máa há a mọ́lé, ṣugbọn kí ó ní òmìnira díẹ̀, kí ó má sì dí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ láti ṣe ìtọ́jú rẹ̀. Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí Fẹliksi ti dé pẹlu Durusila iyawo rẹ̀ tí ó jẹ́ Juu, ó ranṣẹ sí Paulu láti gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa igbagbọ ninu Kristi Jesu lẹ́nu rẹ̀. Nígbà tí Paulu bẹ̀rẹ̀ sí sọ tirẹ̀ nípa ìwà rere, ìkóra-ẹni-níjàánu, ati ìdájọ́ tí ń bọ̀, ẹ̀rù ba Fẹliksi. Ó bá sọ fún Paulu pé, “Ó tó gẹ́ẹ́ lónìí. Máa lọ. Nígbà tí mo bá ráyè n óo tún ranṣẹ pè ọ́.” Sibẹ ó ń retí pé Paulu yóo fún òun ní owó. Nítorí náà, a máa ranṣẹ pè é lemọ́lemọ́ láti bá a sọ̀rọ̀. Lẹ́yìn ọdún meji Pọkiu Fẹstu gba ipò Fẹliksi. Nítorí Fẹliksi ń wá ojurere àwọn Juu, ó fi Paulu sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹta tí Fẹstu dé sí agbègbè ibi iṣẹ́ rẹ̀, ó lọ sí Jerusalẹmu láti Kesaria. Àwọn olórí alufaa ati àwọn aṣiwaju àwọn Juu bá gbé ọ̀rọ̀ Paulu siwaju rẹ̀. Wọ́n ń bẹ̀ ẹ́ pé kí ó ṣe oore kan fún wọn, kí ó fi Paulu ranṣẹ sí Jerusalẹmu. Èrò wọn ni láti dènà dè é, kí wọ́n baà lè pa á. Ṣugbọn Fẹstu dá wọn lóhùn pé, “Àwọn ọmọ-ogun ń ṣọ́ Paulu ní Kesaria; èmi náà kò sì ní pẹ́ pada sibẹ. Ẹ jẹ́ kí àwọn aṣiwaju yín bá mi kálọ kí wọ́n wá sọ bí wọ́n bá ní ẹ̀sùn kan sí i.” Kò lò ju bí ọjọ́ mẹjọ tabi mẹ́wàá lọ pẹlu wọn, ni ó bá pada lọ sí Kesaria. Ní ọjọ́ keji ó jókòó ninu kóòtù, ó pàṣẹ pé kí wọ́n mú Paulu wá. Nígbà tí Paulu dé, àwọn Juu tí wọ́n wá láti Jerusalẹmu tò yí i ká, wọ́n ń ro ẹjọ́ ńláńlá mọ́ ọn lẹ́sẹ̀ lọ́tùn-ún lósì, bẹ́ẹ̀ ni kò sí èyí tí ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ninu gbogbo ẹjọ́ tí wọ́n rò. Nígbà tí Paulu bẹ̀rẹ̀ sí sọ ti ẹnu rẹ̀, ó ní, “N kò ṣe ohunkohun tí ó lòdì sí òfin àwọn Juu tabi sí Tẹmpili; n kò sì ṣẹ Kesari.” Nítorí pé Fẹstu ń wá ojurere àwọn Juu, ó bi Paulu pé, “Ṣé o óo kálọ sí Jerusalẹmu, kí n dá ẹjọ́ yìí níbẹ̀?” Paulu dáhùn ó ní, “Níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ ọba Kesari ni mo gbé dúró, níbẹ̀ ni a níláti dá ẹjọ́ mi. N kò ṣẹ àwọn Juu, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ti mọ̀ dájúdájú. Bí mo bá rú òfin, tabi bí mo bá ṣe ohun tí ó yẹ kí á dá mi lẹ́bi ikú, n kò bẹ̀bẹ̀ pé kí ẹ má pa mí. Ṣugbọn bí kò bá sí ohun kan tí a lè rí dìmú ninu ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn mí, ẹnikẹ́ni kò lè fi mí wá ojurere wọn. Ẹ gbé ẹjọ́ mi lọ siwaju Kesari ọba.” Fẹstu forí-korí pẹlu àwọn olùbádámọ̀ràn rẹ̀, ó wá dáhùn pé, “O ti gbé ẹjọ́ rẹ lọ siwaju ọba Kesari; nítorí náà o gbọdọ̀ lọ sọ́dọ̀ ọba Kesari.” Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, Agiripa ọba ati Berenike wá kí Fẹstu ní Kesaria. Wọ́n pẹ́ díẹ̀ níbẹ̀. Fẹstu wá fi ọ̀rọ̀ Paulu siwaju ọba. Ó ní, “Ọkunrin kan wà níhìn-ín tí Fẹliksi fi sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Nígbà tí mo lọ sí Jerusalẹmu, àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbààgbà àwọn Juu rojọ́ rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀ mí pé kí n dá a lẹ́bi. Mo dá wọn lóhùn pé kì í ṣe àṣà àwọn ará Romu láti fa ẹnikẹ́ni lé àwọn olùfisùn rẹ̀ lọ́wọ́ láì fún un ní anfaani láti fojúkojú pẹlu wọn, kí ó sì sọ ti ẹnu rẹ̀ nípa ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án. Nígbà tí wọ́n bá mi wá síhìn-ín, n kò fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀. Ní ọjọ́ keji mo jókòó ní kóòtù, mo pàṣẹ kí wọ́n mú ọkunrin náà wá. Nígbà tí àwọn tí ó fi ẹ̀sùn kàn án dìde láti sọ̀rọ̀, wọn kò mẹ́nuba irú àwọn ọ̀ràn tí mo rò pé wọn yóo sọ. Àríyànjiyàn nípa ẹ̀sìn oriṣa wọn, ati nípa ẹnìkan tí ń jẹ́ Jesu ni ohun tí wọn ń jà sí. Jesu yìí ti kú, ṣugbọn Paulu ní ó wà láàyè. Ọ̀rọ̀ náà rú mi lójú; mo bá bi ọkunrin náà bí ó bá fẹ́ lọ sí Jerusalẹmu, kí á ṣe ìdájọ́ ọ̀rọ̀ náà níbẹ̀. Ṣugbọn Paulu ní kí á fi òun sílẹ̀ ní ìtìmọ́lé títí Kesari yóo fi lè gbọ́ ẹjọ́ òun. Mo bá pàṣẹ kí wọ́n fi í sílẹ̀ ní ìtìmọ́lé títí tí n óo fi lè fi ranṣẹ sí Kesari.” Agiripa bá wí fún Fẹstu pé, “Èmi fúnra mi fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu ọkunrin náà.” Fẹstu dáhùn ó ní, “Ẹ óo gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀ lọ́la.” Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, Agiripa ati Berenike bá dé pẹlu ayẹyẹ. Wọ́n wọ gbọ̀ngàn ní ààfin pẹlu àwọn ọ̀gágun ati àwọn eniyan jàǹkànjàǹkàn ní ìlú. Fẹstu bá pàṣẹ kí wọ́n mú Paulu wá. Fẹstu wá sọ pé, “Agiripa aláyélúwà ati gbogbo ẹ̀yin eniyan tí ẹ bá wa péjọ níbí. Ọkunrin tí ẹ̀ ń wò yìí ni gbogbo àwọn Juu ní Jerusalẹmu ati níbí ń yan eniyan wá rí mi nípa rẹ̀, tí wọn ń kígbe pé kò yẹ kí ó tún wà láàyè mọ́. Ní tèmi n kò rí ohun kan tí ó ṣe tí ó fi jẹ̀bi ikú. Ṣugbọn nígbà tí òun fúnrarẹ̀ ní kí á gbé ẹjọ́ òun lọ sí ọ̀dọ̀ Kesari, mo pinnu láti fi í ranṣẹ. Ṣugbọn n kò ní ohun kan pàtó láti kọ sí oluwa mi nípa rẹ̀. Ìdí nìyí tí mo fi mú un wá siwaju yín, pàápàá siwaju Agiripa aláyélúwà, kí n lè rí ohun tí n óo kọ nípa rẹ̀ lẹ́yìn tí a bá ti yẹ ọ̀rọ̀ náà wò. Mo rò pé kò bójú mu kí á fi ẹlẹ́wọ̀n ranṣẹ láìsọ ẹ̀sùn tí a fi kàn án.” Agiripa wá yíjú sí Paulu, ó ní, “Ọ̀rọ̀ kàn ọ́. Sọ tìrẹ.” Paulu bá nawọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí ro ẹjọ́ tirẹ̀. Ó ní: “Agiripa Ọba Aláyélúwà, mo ka ara mi sí olóríire pé níwájú yín ni n óo ti dáhùn sí gbogbo ẹjọ́ tí àwọn Juu pè mí lónìí, pàápàá nítorí ẹ mọ gbogbo àṣà àwọn Juu dáradára, ẹ sì mọ àríyànjiyàn tí ó wà láàrin wọn. Nítorí náà mo bẹ̀ yín kí ẹ fi sùúrù gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. “Gbogbo àwọn Juu ni wọ́n mọ̀ bí mo ti lo ìgbésí ayé mi láti ìbẹ̀rẹ̀ ní ìgbà èwe mi nígbà tí mò ń gbé Jerusalẹmu láàrin àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè wa. Ó ti pẹ́ tí wọ́n ti mọ̀ mí. Bí wọn bá fẹ́, wọ́n lè jẹ́rìí sí i pé ọ̀nà àwọn Farisi ni mo tẹ̀lé ninu ẹ̀sìn ìbílẹ̀ wa, ọ̀nà yìí ló sì le jù. Wàyí ò! Ohun tí ó mú mi dúró nílé ẹjọ́ nisinsinyii ni pé mo ní ìrètí pé ìlérí tí Ọlọrun ṣe fún àwọn baba wa yóo ṣẹ. Ìrètí yìí ni àwọn ẹ̀yà mejila tí ó wà ní orílẹ̀-èdè wa ní, tí wọ́n ṣe ń fi ìtara sin Ọlọrun tọ̀sán-tòru. Nítorí ohun tí à ń retí yìí ni àwọn Juu fi ń rojọ́ mi, Kabiyesi! Kí ló ṣe wá di ohun tí ẹnikẹ́ni ninu yín kò lè gbàgbọ́ pé Ọlọrun a máa jí òkú dìde?” “Nígbà kan rí èmi náà rò pé ó jẹ mí lógún láti tako orúkọ Jesu ará Nasarẹti. Kí ni n ò ṣe tán? Mo ṣe díẹ̀ ní Jerusalẹmu. Pupọ ninu àwọn onigbagbọ ni mo tì mọ́lé, lẹ́yìn tí mo ti gba àṣẹ lọ́wọ́ àwọn olórí alufaa. Wọn á máa pa wọ́n báyìí, èmi náà á sì ní bẹ́ẹ̀ gan-an ló yẹ wọ́n. Mò ń lọ láti ilé ìpàdé kan dé ekeji, mo sì ń jẹ wọ́n níyà, bóyá wọn a jẹ́ fẹnu wọn gbẹ̀ṣẹ̀. Ẹ̀tanú náà pọ̀ sí wọn tó bẹ́ẹ̀ tí mo fi lé wọn dé ìlú òkèèrè pàápàá. “Irú eré báyìí ni mò ń sá tí mò fi ń lọ sí Damasku ní ọjọ́ kan, pẹlu ìwé àṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa. Kabiyesi, bí mo ti ń lọ lọ́nà lọ́sàn-án gangan, mo rí ìmọ́lẹ̀ láti ọ̀run tí ó mọ́lẹ̀ ju ti oòrùn lọ, tí ó tàn yí èmi ati àwọn tí ń bá mi lọ ká. Bí gbogbo wa ti ṣubú lulẹ̀, mo gbọ́ ohùn kan tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ ní èdè Heberu. Ó ní, ‘Saulu! Saulu! Kí ló dé tí o fi ń ṣe inúnibíni sí mi? O óo fara pa bí o bá ta igi ẹlẹ́gùn-ún nípàá.’ Mo wá bèèrè pé, ‘Ìwọ ta ni, Oluwa?’ Oluwa bá dáhùn ó ní, ‘Èmi ni Jesu tí ò ń ṣe inúnibíni sí. Dìde nàró. Ohun tí mo fi farahàn ọ́ nìyí: mo ti yàn ọ́ láti jẹ́ iranṣẹ mi, kí o lè jẹ́rìí ohun tí o rí, ati ohun tí n óo fihàn ọ́. N óo gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn eniyan Israẹli ati àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí n óo rán ọ sí. Kí á lè là wọ́n lójú, kí á sì lè yí wọn pada láti inú òkùnkùn sinu ìmọ́lẹ̀, kí á lè gbà wọ́n lọ́wọ́ àṣẹ Satani, kí á sì fi wọ́n lé ọwọ́ Ọlọrun; kí wọ́n lè ní ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nípa gbígbà mí gbọ́; kí wọ́n sì lè ní ogún pẹlu àwọn tí a ti yà sọ́tọ̀ fún Ọlọrun.’ “Nítorí náà, Agiripa Ọba Aláyélúwà, n kò ṣe àìgbọràn sí ìran tí ó ti ọ̀run wá. Ṣugbọn mo kọ́kọ́ waasu fún àwọn tó wà ní Damasku, lẹ́yìn náà mo waasu fún àwọn tó wà ní Jerusalẹmu, ati ní gbogbo ilẹ̀ Judia, ati fún àwọn tí kì í ṣe Juu. Mò ń kéde pé kí wọ́n ronupiwada, kí wọ́n yipada sí Ọlọrun, kí wọn máa ṣe ohun tí ó yẹ ẹni tí ó ti ronupiwada. Ìdí nìyí tí àwọn Juu fi mú mi ninu Tẹmpili, tí wọn ń fẹ́ pa mí. Ṣugbọn Ọlọrun ràn mí lọ́wọ́. Títí di ọjọ́ òní mo ti dúró láti jẹ́rìí fún àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan pataki. N kò sọ ohunkohun yàtọ̀ sí ohun tí àwọn wolii ati Mose sọ pé yóo ṣẹlẹ̀. Èyí ni pé Mesaya níláti jìyà; àtipé òun ni yóo kọ́ jí dìde kúrò ninu òkú tí yóo sì kéde iṣẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún àwọn eniyan Ọlọrun ati fún àwọn tí kì í ṣe Juu.” Bí Paulu ti ń sọ̀rọ̀ báyìí, Fẹstu ké mọ́ ọn pé, “Paulu, orí rẹ dàrú! Ìwé àmọ̀jù ti dà ọ́ lórí rú.” Paulu dáhùn ó ní, “Fẹstu ọlọ́lá, orí mi kò dàrú. Òtítọ́ ọ̀rọ̀ gan-an ni mò ń sọ. Gbogbo nǹkan wọnyi yé Kabiyesi, nítorí náà ni mo ṣe ń sọ ọ́ láìfòyà. Ó dá mi lójú pé kò sí ohun tí ó pamọ́ fún un ninu gbogbo ọ̀rọ̀ yìí. Nítorí kì í ṣe ní kọ̀rọ̀ ni nǹkan wọnyi ti ṣẹlẹ̀. Agiripa Ọba Aláyélúwà, ṣé ẹ gba àwọn wolii gbọ́? Mo mọ̀ pé ẹ gbà wọ́n gbọ́.” Agiripa bá bi Paulu pé, “Kíákíá báyìí ni o rò pé o lè sọ mí di Kristẹni?” Paulu dáhùn, ó ní, “Ẹ̀bẹ̀ tí mò ń bẹ Ọlọrun ni pé, ó pẹ́ ni, ó yá ni, kí ẹ rí bí mo ti rí lónìí, láìṣe ti ẹ̀wọ̀n yìí. Kì í ṣe ẹ̀yin nìkan, ṣugbọn gbogbo àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ mi lónìí.” Agiripa bá dìde pẹlu gomina ati Berenike ati gbogbo àwọn tí ó jókòó pẹlu wọn. Wọ́n bọ́ sápá kan, wọ́n ń sọ fún wọn pé, “Ọkunrin yìí kò ṣe ohunkohun tí ó fi jẹ̀bi ikú tabi ẹ̀wọ̀n.” Agiripa wá sọ fún Fẹstu pé, “À bá dá ọkunrin yìí sílẹ̀ bí kò bá jẹ́ pé ó ti ní kí á gbé ẹjọ́ òun lọ siwaju Kesari.” Nígbà tí wọ́n pinnu láti fi wá ranṣẹ sí Itali, wọ́n fi Paulu ati àwọn ẹlẹ́wọ̀n mìíràn lé balogun ọ̀rún kan tí ó ń jẹ́ Juliọsi lọ́wọ́, ó jẹ́ ọ̀gágun ti ẹgbẹ́ kan tí wọn ń pè ní Ọmọ-ogun Augustu. A bá wọ ọkọ̀ ojú omi kan tí ó ń ti Adiramitu bọ̀ tí ó fẹ́ lọ sí ibi mélòó kan ní Esia. Ọkọ̀ bá ṣí; Arisitakọsi ará Tẹsalonika, ní ilẹ̀ Masedonia, ń bá wa lọ. Ní ọjọ́ keji a gúnlẹ̀ ní Sidoni. Juliọsi ṣe dáradára sí Paulu. Ó jẹ́ kí ó lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, kí wọ́n fún un ní àwọn nǹkan tí ó nílò. Láti ibẹ̀, a ṣíkọ̀, nítorí pé afẹ́fẹ́ ṣọwọ́ òdì sí wa, a gba apá Kipru níbi tí afẹ́fẹ́ kò ti fẹ́ pupọ. A la agbami lọ sí apá èbúté Silisia ati Pamfilia títí a fi dé ìlú Mira ní ilẹ̀ Lisia. Níbẹ̀ ni balogun ọ̀rún tí ó ń mú wa lọ ti rí ọkọ̀ Alẹkisandria kan tí ó ń lọ sí Itali. Ni a bá wọ̀ ọ́. Fún ọpọlọpọ ọjọ́, ọkọ̀ kò lè yára rìn. Tipátipá ni a fi dé Kinidusi. Afẹ́fẹ́ ṣe ọwọ́ òdì sí wa. Ni a bá gba ẹ̀gbẹ́ Kirete níbi tí afẹ́fẹ́ kò ti fẹ́ pupọ. A kọjá ibi tí ilẹ̀ gbọọrọ ti wọ ààrin òkun tí wọn ń pè ní Salimone. Tipátipá ni a fi ń lọ lẹ́bàá èbúté títí a fi dé ibìkan tí wọn ń pè ní Èbúté-rere tí kò jìnnà sí ìlú Lasia. A pẹ́ níbẹ̀. Ewu ni bí a bá fẹ́ máa bá ìrìn àjò wa lọ nítorí ọjọ́ ààwẹ̀ ti kọjá. Paulu bá gbà wọ́n níyànjú; ó ní, “Ẹ̀yin ará, mo wòye pé ewu wà ninu ìrìn àjò yìí. Ọpọlọpọ nǹkan ni yóo ṣòfò: ẹrù inú ọkọ̀, ati ọkọ̀ fúnrarẹ̀. Ewu wà fún gbogbo àwa tí a wà ninu ọkọ̀ pàápàá.” Ṣugbọn ọ̀rọ̀ atukọ̀ ati ẹni tó ni ọkọ̀ wọ ọ̀gágun létí ju ohun tí Paulu sọ lọ. Ibi tí wọ́n wà kì í ṣe ibi tí ó dára láti gbé ní ìgbà òtútù. Nítorí náà pupọ ninu àwọn tí wọ́n wà ninu ọkọ̀ rò pé kí àwọn kúrò níbẹ̀, bóyá wọn yóo lè dé Fonike níbi tí wọn yóo lè dúró ní ìgbà òtútù. Èbúté kan ní Kirete ni Fonike; ó kọjú sí ẹ̀gbẹ́ ìwọ̀ oòrùn gúsù ati ìwọ̀ oòrùn àríwá Kirete. Nígbà tí afẹ́fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ jẹ́jẹ́ láti apá gúsù, wọ́n rò pé ó ti bọ́ sí i fún wọn láti ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe. Wọ́n bá ṣíkọ̀, wọ́n ń pẹ́ ẹ̀bá Kirete lọ. Kò pẹ́ pupọ ni afẹ́fẹ́ líle kan láti erékùṣù náà bá bì lu ọkọ̀. Wọ́n ń pe afẹ́fẹ́ náà ní èyí tí ó wá láti àríwá ìlà oòrùn. Afẹ́fẹ́ líle yìí bá bẹ̀rẹ̀ sí taari ọkọ̀. Nítorí pé kò sí ọ̀nà láti fi yí ọkọ̀, kí ó kọjú sí atẹ́gùn yìí, a fi í sílẹ̀ kí afẹ́fẹ́ máa gbé e lọ. A sinmi díẹ̀ nígbà tí a gba gúsù erékùṣù kékeré kan tí ó ń jẹ́ Kauda kọjá. Níbẹ̀, a fi tipátipá so ọkọ̀ kékeré tí ó wà lára ọkọ̀ ńlá wa, kí ó má baà fọ́. Wọ́n bá fà á sinu ọkọ̀ ńlá, wọ́n wá fi okùn so ó mọ́ ara ọkọ̀ ńlá. Ẹ̀rù ń bà wọ́n kí wọn má forí ọkọ̀ sọ ilẹ̀ iyanrìn ní Sitisi, wọ́n bá ta aṣọ-ọkọ̀, kí atẹ́gùn lè máa gbé ọkọ̀ náà lọ. Ní ọjọ́ keji, nígbà tí ìjì túbọ̀ le pupọ, a bá da ẹrù inú ọkọ̀ sinu òkun. Ní ọjọ́ kẹta, ọwọ́ ara wọn ni wọ́n fi da àwọn ohun èèlò inú ọkọ̀ náà sinu òkun. Fún ọpọlọpọ ọjọ́ ni oòrùn kò ràn tí ìràwọ̀ kò sì yọ. Ìjì ńlá ń jà. A bá sọ ìrètí nù pé a tún lè là mọ́. Lẹ́yìn tí wọ́n ti wà fún ọpọlọpọ ọjọ́, láì jẹun, Paulu dìde dúró láàrin wọn, ó ní, “Ẹ̀yin eniyan, ẹ̀ bá ti gbọ́ tèmi kí ẹ má ṣíkọ̀ ní Kirete. Irú ewu ati òfò yìí ìbá tí sí. Ṣugbọn bí ó ti rí yìí náà, mo gbà yín níyànjú pé kí ẹ ṣara gírí. Ẹ̀mí ẹnikẹ́ni ninu yín kò ní ṣòfò; ọkọ̀ nìkan ni yóo ṣòfò. Nítorí ní alẹ́ àná, angẹli Ọlọrun mi, tí mò ń sìn dúró tì mí, ó ní, ‘Má bẹ̀rù, Paulu. Dandan ni kí o dé iwájú Kesari. Mo fẹ́ kí o mọ̀ pé Ọlọrun ti fi ẹ̀mí gbogbo àwọn ẹni tí ó wọkọ̀ pẹlu rẹ jíǹkí rẹ.’ Nítorí náà ẹ̀yin eniyan, ẹ ṣara gírí, nítorí mo gba Ọlọrun gbọ́ pé bí ó ti sọ fún mi ni yóo rí. Ṣugbọn ọkọ̀ wa yóo fàyà sọlẹ̀ ní erékùṣù kan.” Nígbà tí ó di alẹ́ kẹrinla tí afẹ́fẹ́ ti ń ti ọkọ̀ wa kiri ninu òkun Adiria, àwọn atukọ̀ fura ní òru pé a kò jìnnà sí ilẹ̀. Wọ́n sọ ìwọ̀n sinu òkun, wọ́n rí i pé ó jìn tó ogoji mita. Nígbà tí a sún díẹ̀, wọ́n tún sọ ìwọ̀n sinu òkun, wọ́n rí i pé ó jìn tó ọgbọ̀n mita. Wọ́n wá ń bẹ̀rù pé kí ọkọ̀ má forí sọ òkúta. Wọ́n bá ju irin ìdákọ̀ró mẹrin sinu omi ní ẹ̀yìn ọkọ̀; wọ́n bá ń gbadura pé kí ilẹ̀ tètè mọ́. Àwọn atukọ̀ ń wá bí wọn yóo ti ṣe sálọ kúrò ninu ọkọ̀. Wọ́n bá sọ ọkọ̀ kékeré sórí òkun bí ẹni pé wọ́n fẹ́ sọ ìdákọ̀ró tí ó wà níwájú ọkọ̀ sinu òkun. Paulu wá sọ fún balogun ọ̀rún ati àwọn ọmọ-ogun náà pé, “Bí àwọn ará ibí yìí kò bá dúró ninu ọkọ̀, kò sí bí ẹ ti ṣe lè là.” Àwọn ọmọ-ogun bá gé okùn tí wọ́n fi so ọkọ̀ kékeré náà, wọ́n jẹ́ kí ìgbì gbé e lọ. Nígbà tí ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ mọ́, Paulu gbà wọ́n níyànjú pé kí gbogbo wọn jẹun. Ó ní, “Ó di ọjọ́ mẹrinla lónìí, tí ọkàn yín kò tíì balẹ̀ tí ẹ̀ ń gbààwẹ̀; tí ẹ kò jẹ ohunkohun. Nítorí náà, mo bẹ̀ yín, ẹ jẹun; èyí ṣe pataki bí ẹ ò bá fẹ́ kú. Irun orí ẹnikẹ́ni kò tilẹ̀ ní ṣòfò.” Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, òun náà mú burẹdi, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun níwájú gbogbo wọn, ó bù ú, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ẹ́. Ni gbogbo wọn bá ṣara gírí, àwọn náà bá jẹun. Gbogbo àwa tí a wà ninu ọkọ̀ náà jẹ́ igba ó lé mẹrindinlọgọrin (276). Nígbà tí wọ́n jẹun yó tán, wọ́n da ọkà tí ó kù sinu òkun láti mú kí ọkọ̀ lè fúyẹ́ sí i. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, wọ́n rí èbúté ṣugbọn wọn kò mọ ibẹ̀. Wọ́n wá ṣe akiyesi ibìkan tí òkun ti wọ ààrin ilẹ̀ tí ó ní iyanrìn. Wọ́n rò pé bóyá àwọn lè tukọ̀ dé èbúté ibẹ̀. Wọ́n bá já àwọn ìdákọ̀ró, wọ́n jẹ́ kí wọ́n rì sinu omi. Ní àkókò yìí kan náà, wọ́n tú okùn lára àwọn ajẹ̀ tí wọ́n fi ń tukọ̀. Wọ́n wá ta aṣọ-ọkọ̀ tí ó wà lókè patapata níwájú ọkọ̀. Atẹ́gùn wá ń fẹ́ ọkọ̀ lọ sí èbúté. Ṣugbọn ọkọ̀ rọ́lu ilẹ̀ níbi tí òkun kò jìn, ni ó bá dúró gbọnin. Iwájú ọkọ̀ wọ inú iyanrìn, kò ṣe é yí. Ẹ̀yìn ọkọ̀ kò kanlẹ̀, ìgbì wá bẹ̀rẹ̀ sí fọ́ ọ bí ó ti ń bì lù ú. Àwọn ọmọ-ogun wá ń gbèrò pé kí àwọn pa àwọn ẹlẹ́wọ̀n, kí wọn má baà lúwẹ̀ẹ́ sálọ. Ṣugbọn balogun ọ̀rún kò jẹ́ kí àwọn ọmọ-ogun ṣe ìfẹ́ inú wọn, nítorí pé ó fẹ́ mú Paulu gúnlẹ̀ ní alaafia. Ó pàṣẹ pé kí àwọn tí ó bá lè lúwẹ̀ẹ́ kọ́kọ́ bọ́ sómi, kí wọ́n lúwẹ̀ẹ́ lọ sí èbúté. Kí àwọn yòókù wá tẹ̀lé wọn, kí wọ́n dì mọ́ pákó tabi kí wọ́n dì mọ́ ara ọkọ̀ tí ó ti fọ́. Báyìí ni gbogbo wa ṣe gúnlẹ̀ ní alaafia. Nígbà tí a ti gúnlẹ̀ ní alaafia tán ni a tó mọ̀ pé Mẹlita ni wọ́n ń pe erékùṣù náà. Àwọn ará ibẹ̀ ṣe ìtọ́jú wa lọpọlọpọ. Wọ́n fi ọ̀yàyà gba gbogbo wa. Wọ́n dáná fún wa nítorí pé òjò ti bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀, òtútù sì mú. Nígbà tí Paulu di ìdì igi kan, tí ó dà á sinu iná, bẹ́ẹ̀ ni paramọ́lẹ̀ kan yọ nígbà tí iná rà á, ló bá so mọ́ Paulu lọ́wọ́. Nígbà tí àwọn ará Mẹlita rí ejò náà tí ó ń ṣe dìrọ̀dìrọ̀ ní ọwọ́ Paulu, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Dájúdájú apànìyàn ni ọkunrin yìí. Ó yọ ninu ewu òkun, ṣugbọn Ọlọrun ẹ̀san kò gbà pé kí ó yè.” Paulu kàn gbọn ejò náà sinu iná ni, ohun burúkú kan kò sì ṣẹlẹ̀ sí i. Àwọn eniyan ń retí pé ọwọ́ rẹ̀ yóo wú, tabi pé lójijì yóo ṣubú lulẹ̀, yóo sì kú. Nígbà tí wọ́n retí títí, tí wọn kò rí i kí nǹkankan ṣe é, wọ́n yí èrò wọn pada, wọ́n ní, “Irúnmọlẹ̀ ni!” Ilẹ̀ tí ó wá yí wọn ká jẹ́ ti Pubiliusi, baálẹ̀ erékùṣù náà. Ó gbà wá sílé fún ọjọ́ mẹta, ó sì ṣe wá lálejò. Ní àkókò yìí baba Pubiliusi ń ṣàìsàn: ibà ń ṣe é, ó sì ń ya ìgbẹ́-ọ̀rìn. Paulu bá wọ iyàrá tọ̀ ọ́ lọ. Lẹ́yìn tí ó gbadura, ó gbé ọwọ́ lé e, ó sì wò ó sàn. Nígbà tí èyí ṣẹlẹ̀, àwọn yòókù tí ó ń ṣàìsàn ní erékùṣù náà bá ń wá sọ́dọ̀ Paulu, ó sì ń wò wọ́n sàn. Wọ́n yẹ́ wa sí pupọ. Nígbà tí a óo sì fi ṣíkọ̀, wọ́n fún wa ní àwọn nǹkan tí a lè nílò lọ́nà. Lẹ́yìn oṣù mẹta tí a ti wà níbẹ̀, a wọ ọkọ̀ ojú omi Alẹkisandria kan tí ó ti dúró ní erékùṣù yìí fún ìgbà òtútù. Ó ní ère ìbejì níwájú rẹ̀. Nígbà tí a dé Sirakusi, a dúró níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹta. Láti ibẹ̀ a ṣíkọ̀, a dé Regiumu. Ní ọjọ́ keji, afẹ́fẹ́ kan láti gúsù fẹ́ wá, ni a bá tún ṣíkọ̀. Ní ọjọ́ kẹta a dé Puteoli. A rí àwọn onigbagbọ níbẹ̀. Wọ́n rọ̀ wá kí á dúró lọ́dọ̀ wọn, a bá ṣe ọ̀sẹ̀ kan níbẹ̀. Báyìí ni a ṣe dé Romu. Àwọn onigbagbọ ibẹ̀ ti gbọ́ ìròyìn wa. Wọ́n bá wá pàdé wa lọ́nà, wọ́n dé Ọjà Apiusi ati Ilé-èrò Mẹta. Nígbà tí Paulu rí wọn, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, èyí sì dá a lọ́kàn le. Nígbà tí a wọ Romu, wọ́n gba Paulu láàyè láti wá ilé gbé pẹlu ọmọ-ogun kan tí wọ́n fi ṣọ́ ọ. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹta Paulu pe àwọn aṣiwaju àwọn Juu jọ. Nígbà tí ẹsẹ̀ wọn pé, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin alàgbà, n kò ṣe ohunkohun tí ó lòdì sí àwọn eniyan wa tabi sí àṣà àwọn baba ńlá wa tí wọ́n fi fi mí lé àwọn ará Romu lọ́wọ́ tí wọ́n sì fi mí sinu ẹ̀wọ̀n láti Jerusalẹmu. Nígbà tí wọ́n wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu mi, wọ́n fẹ́ dá mi sílẹ̀ nítorí wọn kò rí ohunkohun tí mo ṣe tí wọ́n fi lè dá mi lẹ́bi ikú. Ṣugbọn nígbà tí àwọn Juu kò gbà pé kí wọ́n dá mi sílẹ̀, kò sí ohun tí mo tún lè ṣe jù pé kí n gbé ẹjọ́ mi wá siwaju Kesari lọ. Kì í ṣe pé mo ní ẹjọ́ kankan láti bá orílẹ̀-èdè wa rò. Ìdí nìyí tí mo fi ranṣẹ pè yín láti ri yín kí n sì ba yín sọ̀rọ̀; nítorí ohun tí Israẹli ń retí ni wọ́n ṣe fi ẹ̀wọ̀n so mí báyìí.” Wọ́n dá a lóhùn pé, “A kò rí ìwé gbà nípa rẹ láti Judia; bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni ninu àwọn ará wa kò débí láti ròyìn rẹ tabi láti sọ̀rọ̀ rẹ ní ibi. A rò pé ó dára kí á gbọ́ ohun tí o ní lọ́kàn, nítorí pé ó ti dé etígbọ̀ọ́ wa pé níbi gbogbo ni àwọn eniyan lòdì sí ẹgbẹ́ tí ó yàtọ̀ yìí.” Wọ́n bá dá ọjọ́ tí wọn yóo wá fún un. Nígbà tí ọjọ́ pé, pupọ ninu wọn wá kí i. Ó bá dá ọ̀rọ̀ sílẹ̀, ó ń fi tẹ̀dùntẹ̀dùn ṣe àlàyé ìjọba Ọlọrun fún wọn, ó sì ń fi ẹ̀rí tí ó wà ninu ìwé Òfin Mose ati ìwé wolii nípa Jesu hàn wọ́n láti òwúrọ̀ títí di ìrọ̀lẹ́. Àwọn mìíràn gba ohun tí ó sọ gbọ́, ṣugbọn àwọn mìíràn kò gbàgbọ́. Nígbà tí ohùn wọn kò dọ́gba láàrin ara wọn, wọ́n bá ń túká lọ. Paulu wá tún sọ gbolohun kan, ó ní, “Òtítọ́ ni Ẹ̀mí Mímọ́ sọ láti ẹnu wolii Aisaya sí àwọn baba-ńlá yín. Ó ní, ‘Lọ sọ fún àwọn eniyan yìí pé: Ẹ óo fetí yín gbọ́, ṣugbọn kò ní ye yín; Ẹ óo wò ó títí, ṣugbọn ẹ kò ní mọ̀ ọ́n. Nítorí ọkàn àwọn eniyan yìí kò ṣí; wọ́n ti di alágbọ̀ọ́ya, wọ́n ti dijú. Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọn ìbá fi ojú wọn ríran, wọn ìbá fetí gbọ́ràn, òye ìbá yé wọn, wọn ìbá yipada; èmi ìbá sì wò wọ́n sàn.’ “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé a ti rán iṣẹ́ ìgbàlà Ọlọrun yìí sí àwọn tí kì í ṣe Juu. Àwọn ní tiwọn yóo gbọ́.” Nígbà tí Paulu ti sọ báyìí tán, àwọn Juu túká, wọ́n ń bá ara wọn jiyàn kíkankíkan. Fún ọdún meji gbáko ni Paulu fi gbé ninu ilé tí ó gbà fúnra rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó ń gba gbogbo àwọn tí ó ń wá rí i. Ó ń waasu ìjọba Ọlọrun. Ó ń kọ́ àwọn eniyan nípa Oluwa Jesu Kristi láì bẹ̀rù ohunkohun. Ẹnikẹ́ni kò sì dí i lọ́wọ́. Èmi Paulu, iranṣẹ Kristi Jesu, ni mò ń kọ ìwé yìí. Ọlọrun pè mí, ó fi mí ṣe òjíṣẹ́, ó sì yà mí sọ́tọ̀ láti máa waasu ìyìn rere rẹ̀. Bí a bá wo inú Ìwé Mímọ́, a óo rí i pé àwọn wolii ti kéde ìyìn rere náà tẹ́lẹ̀ rí. Ìyìn rere Ọmọ Ọlọrun tí a bí ninu ìdílé Dafidi nípa ti ara. Ọmọ rẹ̀ yìí ni Ọlọrun fi agbára Ẹ̀mí Mímọ́ yàn nígbà tí ó jí i dìde kúrò ninu òkú. Òun náà ni Jesu Kristi Oluwa wa, nípa ẹni tí a ti rí oore-ọ̀fẹ́ gbà, tí a sì gba iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní orúkọ rẹ̀, pé kí gbogbo eniyan lè gba Jesu gbọ́, kí wọ́n sì gbọ́ràn sí i lẹ́nu. Ẹ̀yin tí mò ń kọ ìwé yìí sí náà wà lára àwọn tí Jesu Kristi pè. Gbogbo ẹ̀yin àyànfẹ́ Ọlọrun tí ẹ wà ní Romu, ẹ̀yin tí a pè láti jẹ́ eniyan ọ̀tọ̀. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba wa ati Oluwa Jesu Kristi, kí ó wà pẹlu yín. Kí á tó máa bá ọ̀rọ̀ wa lọ, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun mi nípasẹ̀ Jesu Kristi nítorí gbogbo yín; nítorí àwọn eniyan ń ròyìn igbagbọ yín ní gbogbo ayé. Ọlọrun, tí mò ń fọkàn sìn bí mo ti ń waasu ìyìn rere Ọmọ rẹ̀, ni ẹlẹ́rìí mi pé mò ń ranti yín láì sinmi. Mo sì ń bẹ̀bẹ̀ nígbà gbogbo ninu adura mi pé, ó pẹ́ ni, ó yá ni, kí n rí ààyè láti wá sọ́dọ̀ yín, bí Ọlọrun bá fẹ́. Mò ń dàníyàn láti ri yín, kí n lè fun yín ní ẹ̀bùn ẹ̀mí tí yóo túbọ̀ fun yín lágbára. Ohun tí mò ń sọ ni pé mo fẹ́ wà láàrin yín kí n baà lè ní ìwúrí nípa igbagbọ yín, kí ẹ̀yin náà ní ìwúrí nípa igbagbọ mi. Kò yẹ kí ẹ má mọ̀, ará, pé ní ìgbà pupọ ni mo ti fẹ́ wá sọ́dọ̀ yín, kí n lè ní èso láàrin yín bí mo ti ní láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, ṣugbọn nǹkankan ti ń dí mi lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ títí di àkókò yìí. Nítorí pé ati àwọn Giriki tí wọ́n jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n, ati àwọn kògbédè tí kò mọ nǹkan, gbogbo wọn ni mo jẹ ní gbèsè. Ìdí rẹ̀ nìyí tí mo ṣe ń dàníyàn láti waasu ìyìn rere fún ẹ̀yin tí ẹ wà ní Romu náà. Ojú kò tì mí láti waasu ìyìn rere Jesu, nítorí ìyìn rere yìí ni agbára Ọlọrun, tí a fi ń gba gbogbo àwọn tí ó bá gbà á gbọ́ là. Ó kọ́kọ́ lo agbára yìí láàrin àwọn Juu, lẹ́yìn náà ó lò ó láàrin àwọn Giriki. Ninu ìyìn rere yìí ni a ti ń fi ọ̀nà tí Ọlọrun fi ń dá eniyan láre hàn wá: nípa igbagbọ ni, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Nítorí igbagbọ ni ẹni tí a bá dá láre yóo fi yè.” Ojú ọ̀run ti ṣí sílẹ̀, Ọlọrun sì ń tú ibinu rẹ̀ sórí gbogbo eniyan nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ati ìwà burúkú tí wọn ń hù, tí wọ́n fi ń ṣe ìdènà fún òtítọ́. Nítorí ohun tí eniyan lè mọ̀ nípa Ọlọrun ti hàn sí wọn, Ọlọrun ni ó ti fihàn wọ́n. Láti ìgbà tí Ọlọrun ti dá ayé ni ìwà ati ìṣe Ọlọrun, tí a kò lè fi ojú rí ati agbára ayérayé rẹ̀, ti hàn gedegbe ninu àwọn ohun tí ó dá. Nítorí èyí, irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀ kò ní àwáwí. Wọ́n mọ Ọlọrun, ṣugbọn wọn kò júbà rẹ̀ bí Ọlọrun, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, gbogbo èrò wọn di asán, òye ọkàn wọn sì ṣókùnkùn. Wọ́n ń ṣe bí ẹni pé wọ́n gbọ́n, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n ya òmùgọ̀. Wọ́n yí ògo Ọlọrun tí kò lè bàjẹ́ pada sí àwòrán ẹ̀dá tí yóo bàjẹ́; bíi àwòrán eniyan, ẹyẹ, ẹranko ati ejò. Nítorí náà Ọlọrun fi wọ́n sílẹ̀ láti máa ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn wọn. Wọ́n yí òtítọ́ Ọlọrun pada sí irọ́. Wọ́n ń bọ nǹkan tí Ọlọrun dá, wọ́n ń tẹríba fún wọn, dípò èyí tí wọn ìbá fi máa sin ẹni tí ó dá wọn, ẹni tí ìyìn yẹ fún títí lae. Amin. Nítorí náà, Ọlọrun fi wọ́n sílẹ̀ fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tí ó ti eniyan lójú. Àwọn obinrin wọn ń bá ara wọn ṣe ohun tí kò bójú mu. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọkunrin wọn. Dípò tí ọkunrin ìbá máa fi bá obinrin lòpọ̀, ọkunrin ati ọkunrin ni wọ́n ń dìde sí ara wọn ninu ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn. Ọkunrin ń bá ọkunrin ṣe ohun ìtìjú, wọ́n wá ń jèrè ìṣekúṣe wọn. Nígbà tí wọn kò ka ìmọ̀ Ọlọrun sí, Ọlọrun fi wọ́n sílẹ̀ pẹlu ọkàn wọn tí kò tọ́, kí wọn máa ṣe àwọn ohun tí kò yẹ. Wọ́n wá kún fún oríṣìíríṣìí ìwà burúkú: ojúkòkòrò, ìkà, owú jíjẹ, ìpànìyàn, ìrúkèrúdò, ẹ̀tàn, inú burúkú. Olófòófó ni wọ́n, ati abanijẹ́; wọn kò sì bọ̀wọ̀ fún Ọlọrun. Wọ́n jẹ́ aláfojúdi, onigbeeraga, afọ́nnu, ati elérò burúkú; wọn kì í gbọ́ràn sí òbí lẹ́nu; wọn kò sì ní ẹ̀rí ọkàn. Aláìṣeégbẹ́kẹ̀lé ni wọ́n, aláìnífẹ̀ẹ́, ati aláìláàánú. Wọ́n mọ ìlànà ti Ọlọrun; wọ́n mọ̀ pé ikú ni ó tọ́ sí àwọn tí wọn bá ń hu irú ìwà wọnyi; sibẹ kì í ṣe pé wọ́n ń hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ nìkan, wọ́n tún ń kan sáárá sí àwọn tí ń hùwà bẹ́ẹ̀. Kò sí àwáwí kankan fún ọ, ìwọ tí ò ń dá ẹlòmíràn lẹ́jọ́, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́. Nǹkan gan-an tí ò ń torí rẹ̀ dá ẹlòmíràn lẹ́jọ́ ni o fi ń dá ara rẹ lẹ́bi. Nítorí ìwọ náà tí ò ń dáni lẹ́jọ́ ń ṣe àwọn nǹkan gan-an tí ò ń dá ẹlòmíràn lẹ́bi fún. Ṣugbọn a mọ̀ pé Ọlọrun ní ẹ̀tọ́ láti ṣe ìdájọ́ àwọn tí ń ṣe irú nǹkan wọnyi. Ìwọ tí ò ń dá àwọn ẹlòmíràn tí ó ń ṣe nǹkan wọnyi lẹ́jọ́, tí ìwọ alára sì ń ṣe nǹkankan náà, ṣé o wá rò pé ìwọ óo bọ́ ninu ìdájọ́ Ọlọrun ni? Àbí o fi ojú tẹmbẹlu ọpọlọpọ oore Ọlọrun ni, ati ìfaradà rẹ̀ ati sùúrù rẹ̀? O kò mọ̀ pé kí o lè ronupiwada ni gbogbo oore tí Ọlọrun ń ṣe, Ṣugbọn nípa oríkunkun ati agídí ọkàn rẹ, ò ń fi ibinu Ọlọrun pamọ́ fún ara rẹ títí di ọjọ́ ibinu ati ìgbà tí ìdájọ́ òdodo Ọlọrun yóo dé. Ọlọrun yóo san ẹ̀san fún olukuluku gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀; yóo fi ìyè ainipẹkun fún àwọn tí ń fi sùúrù ṣe iṣẹ́ rere nípa lílépa àwọn nǹkan tí ó lógo, tí ó sì lọ́lá, àwọn nǹkan tí kò lè bàjẹ́. Ṣugbọn ní ti àwọn tí ó jẹ́ pé ti ara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀, ati àwọn tí kò gba òtítọ́, àwọn tí wọ́n gba ohun burúkú, Ọlọrun yóo fi ibinu ati ìrúnú rẹ̀ hàn wọ́n; yóo mú ìpọ́njú ati ìṣòro bá gbogbo àwọn tí ó ń ṣe iṣẹ́ ibi. Àwọn Juu ni yóo kọ́kọ́ kàn, lẹ́yìn náà àwọn Giriki. Ṣugbọn yóo fi ògo, ọlá ati alaafia fún gbogbo àwọn tí ó ń ṣe rere. Àwọn Juu ni yóo kọ́kọ́ fún, lẹ́yìn náà yóo fún àwọn Giriki. Nítorí Ọlọrun kì í ṣe ojuṣaaju. Gbogbo àwọn tí wọ́n bá dẹ́ṣẹ̀ láì lófin, láì lófin náà ni wọn yóo kú. Gbogbo àwọn tí wọ́n mọ Òfin, tí wọ́n sì dẹ́ṣẹ̀, òfin náà ni a óo fi ṣe ìdájọ́ wọn. Kì í ṣe àwọn tí wọ́n gbọ́ ohun tí Òfin sọ ni Ọlọrun ń dá láre, àwọn tí wọn ń ṣe ohun tí Òfin sọ ni. Nígbà tí àwọn tí kì í ṣe Juu tí kò mọ Òfin bá ń ṣe ohun tí Òfin sọ bí nǹkan àmútọ̀runwá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò mọ Òfin, wọ́n di òfin fún ara wọn. Irú àwọn wọnyi fihàn pé a ti kọ iṣẹ́ ti Òfin sinu ọkàn wọn. Ẹ̀rí ọkàn wọn ń ṣiṣẹ́ ninu wọn: àwọn èrò oríṣìíríṣìí tí ó wà ninu wọn yóo máa dá wọn láre tabi kí ó máa dá wọn lẹ́bi, ní ọjọ́ tí Ọlọrun yóo rán Jesu láti ṣe ìdájọ́ ohun ìkọ̀kọ̀ gbogbo tí ó wà ninu eniyan gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere tí mò ń waasu. Ìwọ tí ò ń pe ara rẹ ní Juu, o gbójú lé Òfin, o wá ń fọ́nnu pé o mọ Ọlọrun. O mọ ohun tí Ọlọrun fẹ́. O mọ àwọn ohun tí ó dára jù nítorí a ti fi Òfin kọ́ ọ. O dá ara rẹ lójú bí ẹni tí ó jẹ́ amọ̀nà fún àwọn afọ́jú, ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí ó wà ninu òkùnkùn. O pe ara rẹ ní ẹni tí ó lè bá àwọn tí kò gbọ́n wí, olùkọ́ àwọn ọ̀dọ́, ẹni tí ó mọ àwọn nǹkan tí ó jẹ́ kókó ati òtítọ́ tí ó wà ninu Òfin. Ìwọ tí ò ń kọ́ ẹlòmíràn, ṣé o kò ní kọ́ ara rẹ? Ìwọ tí ò ń waasu pé kí eniyan má jalè, ṣé ìwọ náà kì í jalè? Ìwọ tí o sọ pé kí eniyan má ṣe àgbèrè, ṣé ìwọ náà kì í ṣe àgbèrè? Ìwọ tí o kórìíra oriṣa, ṣé o kì í ja ilé ìbọ̀rìṣà lólè? Ìwọ tí ò ń fọ́nnu pé o mọ Òfin, ṣé o kì í mú ẹ̀gàn bá Ọlọrun nípa rírú Òfin? Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Orúkọ Ọlọrun di ohun ìṣáátá láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu nítorí yín.” Ilà tí o kọ ní anfaani, bí o bá ń pa Òfin mọ́. Ṣugbọn tí o bá rú Òfin, bí àìkọlà ni ìkọlà rẹ rí. Ǹjẹ́ bí aláìkọlà bá ń pa àwọn ìlànà òdodo tí ó wà ninu Òfin mọ́, a kò ha ní ka àìkọlà rẹ̀ sí ìkọlà? Ẹni tí a bí ní aláìkọlà tí ó ń pa Òfin mọ́, ó mú ìtìjú bá ìwọ tí a kọ Òfin sílẹ̀ fún, tí o kọlà, ṣugbọn sibẹ tí o jẹ́ arúfin. Kì í ṣe nǹkan ti òde ara ni eniyan fi ń jẹ́ Juu, bẹ́ẹ̀ ni ìkọlà kì í ṣe kí á fabẹ gé ara. Ṣugbọn láti jẹ́ Juu tòótọ́ jẹ́ ohun àtinúwá; ìkọlà jẹ́ nǹkan ti ọkàn. Nǹkan ti ẹ̀mí ni, kì í ṣe ti inú ìwé. Ìyìn irú ẹni bẹ́ẹ̀ wà lọ́dọ̀ Ọlọrun, kì í ṣe ọ̀dọ̀ eniyan. Ọ̀nà wo wá ni àwọn Juu fi sàn ju àwọn orílẹ̀-èdè yòókù lọ? Kí ni anfaani ìkọlà? Ó pọ̀ pupọ ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà. Ekinni, àwọn Juu ni Ọlọrun fún ní ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ rẹ̀. Ẹ lè wá sọ pé, “Anfaani wo ni ó wà ninu èyí nígbà tí àwọn mìíràn ninu wọn kò gbàgbọ́? Ǹjẹ́ aigbagbọ wọn kò sọ ìṣòtítọ́ Ọlọrun di òtúbáńtẹ́?” Rárá o! Ọlọrun níláti jẹ́ olóòótọ́ bí gbogbo eniyan bá tilẹ̀ di onírọ́. Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Kí ìwọ Ọlọrun lè jẹ́ olódodo ninu ọ̀rọ̀ rẹ, kí o lè borí nígbà tí wọ́n bá pè ọ́ lẹ́jọ́.” Bí aiṣododo wa bá mú kí òdodo Ọlọrun fi ẹsẹ̀ múlẹ̀, kí ni kí á wá wí? Ṣé Ọlọrun kò ṣe ẹ̀tọ́ láti bínú sí wa ni? (Mò ń sọ̀rọ̀ bí ẹni pé eniyan ni Ọlọrun.) Rárá o! Bí Ọlọrun kò bá ní ẹ̀tọ́ láti bínú, báwo ni yóo ṣe wá ṣe ìdájọ́ aráyé? Bí aiṣotitọ mi bá mú kí ògo òtítọ́ Ọlọrun túbọ̀ hàn, kí ni ṣe tí a tún fi ń dá mi lẹ́bi bí ẹlẹ́ṣẹ̀? Ṣé, “Kí á kúkú máa ṣe ibi kí rere lè ti ibẹ̀ jáde?” Bí àwọn onísọkúsọ kan ti ń sọ pé à ń sọ. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ yẹ fún ìdálẹ́bi. Kí ni kí á rí dìmú ninu ọ̀rọ̀ yìí? Ṣé àwa Juu sàn ju àwọn orílẹ̀-èdè yòókù lọ ni? Rárá o! Nítorí a ti wí ṣáájú pé ati Juu ati Giriki, gbogbo wọn ni ó wà ní ìkáwọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Ó wà ní àkọsílẹ̀ bẹ́ẹ̀ pé, “Kò sí ẹnìkan tí ó jẹ́ olódodo; kò sí ẹnìkankan. Kò sí ẹni tí òye yé, kò sí ẹni tí ó ń wá Ọlọrun. Gbogbo wọn ti yapa kúrò lójú ọ̀nà, gbogbo wọn kò níláárí mọ́, kò sí ẹni tí ó ń ṣe rere, kò sí ẹnìkan. Ibojì tí ó yanu sílẹ̀ ni ọ̀nà ọ̀fun wọn, ẹ̀tàn kún ẹnu wọn; oró paramọ́lẹ̀ wà létè wọn; ẹnu wọn kún fún èpè ati ọ̀rọ̀ burúkú. Ẹsẹ̀ wọn yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀. Ọ̀nà jamba ati òṣì ni wọ́n ń rìn. Wọn kò mọ ọ̀nà alaafia. Kò sí ìbẹ̀rù Ọlọrun ní ọkàn wọn.” A mọ̀ pé ohunkohun tí Òfin bá wí, ó wà fún àwọn tí ó mọ Òfin ni, kí ẹnikẹ́ni má ṣe rí àwáwí wí, kí gbogbo aráyé lè wà lábẹ́ ìdájọ́ Ọlọrun. Nítorí gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀, bí a bá mú Òfin tí a fi díwọ̀n iṣẹ́ ọmọ eniyan, kò sí ẹ̀dá kan tí a óo dá láre níwájú Ọlọrun. Nítorí òfin níí mú kí eniyan mọ ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́ṣẹ̀. Ṣugbọn ní àkókò yìí, ọ̀nà tí Ọlọrun fi ń dá eniyan láre ti hàn láìsí Òfin, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àkọsílẹ̀ ti Òfin ati ti àwọn wolii Ọlọrun jẹ́rìí sí i. Gbogbo àwọn tí ó bá gba Jesu gbọ́ yóo yege lọ́dọ̀ Ọlọrun láìsí ìyàtọ̀ kan. Nítorí gbogbo eniyan ló ti dẹ́ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọrun. Gbogbo wọn ni Ọlọrun ti ṣe lóore: ó dá wọn láre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa ìràpadà tí Kristi Jesu ṣe. Jesu yìí ni Ọlọrun fi ṣe ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹni tí ó bá gbàgbọ́, nípa ikú rẹ̀. Èyí ni láti fi ọ̀nà tí Ọlọrun yóo fi dá eniyan láre hàn, nítorí pé ó fi ojú fo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àtijọ́ dá, nípa ìyọ́nú rẹ̀, kí ó lè fi òdodo rẹ̀ hàn ní àkókò yìí, kí ó lè hàn pé olódodo ni òun, ati pé òun ń dá ẹni tí ó bá gba Jesu gbọ́ láre. *** Ààyè ìgbéraga dà? Kò sí rárá. Nípa irú ìlànà wo ni kò fi sí mọ́? Nípa iṣẹ́ Òfin ni bí? Rárá o! Nípa ìlànà ti igbagbọ ni. Nítorí ohun tí a rí ni pé nípa igbagbọ ni Ọlọrun ń dá eniyan láre, kì í ṣe nípa pípa Òfin mọ́. Àbí ti àwọn Juu nìkan ni Ọlọrun, kì í ṣe ti àwọn orílẹ̀-èdè yòókù? Dájúdájú Ọlọrun àwọn Juu ati ti àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ni. Nígbà tí ó jẹ́ pé Ọlọrun kanṣoṣo ni ó wà, òun ni ó sì ń dá àwọn tí ó kọlà láre nípa igbagbọ, tí ó tún ń dá àwọn tí kò kọlà láre nípa igbagbọ bákan náà. Ṣé Òfin wá di òtúbáńtẹ́ nítorí igbagbọ ni? Rárá o! A túbọ̀ fi ìdí Òfin múlẹ̀ ni. Kí ni kí á wí nípa Abrahamu baba-ńlá wa nípa ti ara? Kí ni ìrírí rẹ̀? Bí ó bá jẹ́ pé nítorí ohun tí ó ṣe ni Ọlọrun fi dá a láre, ìwọ̀nba ni ohun tí ó lè fi ṣe ìgbéraga. Ṣugbọn kò lè fọ́nnu níwájú Ọlọrun. Ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ ni pé, “Abrahamu gba Ọlọrun gbọ́, Ọlọrun sì kà á sí ẹni rere.” A kò lè pe èrè tí òṣìṣẹ́ bá gbà ní ẹ̀bùn; ẹ̀tọ́ rẹ̀ ni. Ṣugbọn ẹni tí kò ṣe nǹkankan, ṣugbọn tí ó ṣá ní igbagbọ sí ẹni tí ó ń dá ẹni tí kò yẹ láre, Ọlọrun kà á sí ẹni rere nípa igbagbọ rẹ̀. Dafidi náà sọ̀rọ̀ nípa oríire ẹni tí Ọlọrun kà sí ẹni rere, láìwo iṣẹ́ tí ó ṣe. Ó ní, “Ẹni tí Ọlọrun bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì, tí Ọlọrun bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀, ó ṣoríire. Ẹni tí Oluwa kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí lọ́rùn sì ṣoríire.” Ṣé ẹni tí ó kọlà nìkan ni ó ṣoríire ni, tabi ati ẹni tí kò kọlà náà? Ohun tí a sọ ni pé, “Ọlọrun ka igbagbọ sí iṣẹ́ rere fún Abrahamu.” Ipò wo ni ó wà tí Ọlọrun fi kà á sí ẹni rere: lẹ́yìn tí ó ti kọlà ni tabi kí ó tó kọlà? Kì í ṣe lẹ́yìn tí ó ti kọlà, kí ó tó kọlà ni. Ó gba àmì ìkọlà bí ẹ̀rí iṣẹ́ rere nípa igbagbọ tí ó ní nígbà tí kò ì tíì kọlà. Nítorí èyí, ó di baba fún gbogbo àwọn tí ó ní igbagbọ láì kọlà, kí Ọlọrun lè kà wọ́n sí ẹni rere; ó sì di baba fún àwọn tí ó kọlà ṣugbọn tí wọn kò gbẹ́kẹ̀lé ilà tí wọ́n kọ, ṣugbọn tí wọn ń rìn ní irú ọ̀nà igbagbọ tí baba wa Abrahamu ní kí ó tó kọlà. Nítorí kì í ṣe nítorí pé Abrahamu pa Òfin mọ́ ni Ọlọrun fi ṣe ìlérí fún òun ati ìran rẹ̀ pé yóo jogún ayé; nítorí ó gba Ọlọrun gbọ́ ni, Ọlọrun sì kà á sí ẹni rere. Nítorí bí ó bá jẹ́ pé àwọn tí ń tẹ̀lé ètò Òfin ni yóo jogún ìlérí Ọlọrun, a jẹ́ pé ọ̀ràn àwọn tí ó dúró lórí igbagbọ di òfo, ìlérí Ọlọrun sì di òtúbáńtẹ́. Nítorí òfin ni ó ń mú ibinu Ọlọrun wá. Ṣugbọn níbi tí kò bá sí òfin, kò sí ẹ̀ṣẹ̀. Ìdí nìyí tí ìlérí náà fi jẹ́ ti igbagbọ, kí ó lè jẹ́ ọ̀fẹ́, kí ó sì lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ fún gbogbo ọmọ Abrahamu. Kì í ṣe fún àwọn tí ó gba ètò ti Òfin nìkan, bíkòṣe fún ẹni tí ó bá ní irú igbagbọ tí Abrahamu ẹni tí ó jẹ́ baba fún gbogbo wa ní. Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Mo ti yàn ọ́ láti di baba fún ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè.” Níwájú Ọlọrun ni Abrahamu wà nígbà tí ó gba ìlérí yìí, níwájú Ọlọrun tí ó gbẹ́kẹ̀lé, Ọlọrun tí ó ń sọ òkú di alààyè, Ọlọrun tí ó ń pe àwọn ohun tí kò ì tíì sí jáde bí ẹni pé wọ́n wá. Abrahamu retí títí, ó gbàgbọ́ pé òun yóo di baba fún ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti wí, pé, “Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ rẹ yóo rí.” Igbagbọ rẹ̀ kò yẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ro ti ara rẹ̀ tí ó ti di òkú tán, (nítorí ó ti tó ẹni ọgọrun-un ọdún) ó tún ro ti Sara tí ó yàgàn. Kò fi aigbagbọ ṣiyèméjì sí ìlérí Ọlọrun. Kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ni igbagbọ rẹ̀ túbọ̀ lágbára sí i, ó fi ògo fún Ọlọrun nítorí pé ó dá a lójú pé ẹni tí ó ṣe ìlérí lè mú un ṣẹ. Ìdí rẹ̀ nìyí tí Ọlọrun fi ka igbagbọ rẹ̀ sí iṣẹ́ rere fún un. Ṣugbọn kì í ṣe nípa òun nìkan ṣoṣo ni a kọ ọ́ pé a ka igbagbọ sí iṣẹ́ rere. A kọ ọ́ nítorí ti àwa náà tí a óo kà sí ẹni rere, gbogbo àwa tí a ní igbagbọ ninu ẹni tí ó jí Jesu Oluwa wa dìde kúrò ninu òkú, ẹni tí ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, tí a sì jí dìde fún ìdáláre wa. Níwọ̀n ìgbà tí a ti dá wa láre nítorí pé a gba Ọlọrun gbọ́, kò sí ìjà mọ́ láàrin àwa ati Ọlọrun: Jesu Kristi Oluwa wa ti parí ìjà. Ọpẹ́lọpẹ́ rẹ̀ ni a fi rí ọ̀nà gbà dé ipò oore-ọ̀fẹ́ tí a wà ninu rẹ̀ yìí. A wá ń yọ̀ ninu ògo Ọlọrun tí à ń retí. Èyí nìkan kọ́. A tún ń fi àwọn ìṣòro wa ṣe ọlá, nítorí a mọ̀ pé àyọrísí ìṣòro ni ìfaradà; àyọrísí ìfaradà ni ìyege ìdánwò; àyọrísí ìyege ìdánwò ni ìrètí. Ìrètí irú èyí kì í ṣe ohun tí yóo dójú tì wá, nítorí a ti tú ìfẹ́ Ọlọrun dà sí wa lọ́kàn nípa Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó fún wa. Nítorí nígbà tí a jẹ́ aláìlera, ní àkókò tí ó wọ̀, Kristi kú fún àwa tí kò ka Ọlọrun sí. Bóyá ni a lè rí ẹni tí yóo fẹ́ kú fún olódodo. Ṣugbọn ó ṣeéṣe kí á rí ẹni tí yóo ní ìgboyà láti kú fún eniyan rere. Ṣugbọn Ọlọrun fihàn wá pé òun fẹ́ràn wa ní ti pé nígbà tí a ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa. Bí ó bá lè kú fún wa nígbà tí a sì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, nisinsinyii tí Ọlọrun ti dá wa láre nítorí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, yóo fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, a óo sì torí rẹ̀ gbà wá kúrò ninu ibinu tí ń bọ̀. Bí ikú Ọmọ Ọlọrun bá sọ àwa tí a jẹ́ ọ̀tá Ọlọrun di ọ̀rẹ́ rẹ̀, nígbà yìí tí a wá di ọ̀rẹ́ Ọlọrun tán, ajinde ọmọ rẹ̀ yóo gbà wá là ju tàtẹ̀yìnwá lọ. Kì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣugbọn à ń yọ̀ ninu Ọlọrun nítorí ohun tí ó ṣe nípa Oluwa wa Jesu Kristi, ẹni tí ó sọ wá di ọ̀rẹ́ Ọlọrun ní àkókò yìí. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe ti ipasẹ̀ ẹnìkan wọ inú ayé, tí ikú sì ti ipasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wọlé, bẹ́ẹ̀ náà ni ikú ṣe ran gbogbo eniyan, nítorí pé gbogbo eniyan ni ó ṣẹ̀. Ẹ̀ṣẹ̀ ni ó ṣiwaju Òfin dáyé, bẹ́ẹ̀ bí kò bá sí òfin a kì í ka ẹ̀ṣẹ̀ sí eniyan lọ́rùn. Ṣugbọn ikú ti jọba ní tirẹ̀ láti ìgbà Adamu títí dé ìgbà Mose, àwọn tí kò tilẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ nípa rírú òfin bíi Adamu, pẹlu àwọn tí ikú pa, Adamu tí ó jẹ́ àpẹẹrẹ irú ẹni tó ń bọ̀. Kì í ṣe bí eniyan ṣe rú òfin tó ni Ọlọrun fi ń wọn ìfẹ́ ati àánú rẹ̀. Bí gbogbo eniyan bá jogún ikú nítorí aṣemáṣe ẹnìkan, oore-ọ̀fẹ́ ati àánú tí Ọlọrun fún gbogbo eniyan láti ọwọ́ ẹnìkan, àní Jesu Kristi, ó pọ̀ pupọ; ó pọ̀ ju ogún ikú lọ. Kì í ṣe ẹnìkan tí ó dẹ́ṣẹ̀ ni Ọlọrun ń wò kí ó tó ta àwọn eniyan lọ́rẹ. Ẹnìkan ló fa ìdájọ́ Ọlọrun. Ẹ̀bi ni a sì rí gbà ninu rẹ̀. Ṣugbọn àánú tí Ọlọrun fún wa dípò ọpọlọpọ aṣemáṣe wa, ìdáláre ni ó yọrí sí. Bí ikú bá torí òfin tí ẹnìkan rú jọba lé wa lórí, àwọn tí ó ti gba ibukun lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, tí wọ́n sì gba ìdáláre lọ́fẹ̀ẹ́, yóo ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ: wọn óo jọba, wọn óo sì yè pẹlu àṣẹ ẹnìkan, Jesu Kristi. Nítorí náà, bí òfin tí ẹnìkan rú ṣe ti gbogbo ọmọ aráyé sinu ìdájọ́ ikú, bẹ́ẹ̀ náà ni iṣẹ́ rere ẹnìkan yóo yọ gbogbo ọmọ aráyé ninu ìdájọ́ ikú sí ìyè. Bí a ti sọ gbogbo eniyan di ẹlẹ́ṣẹ̀ nítorí àìgbọràn ẹnìkan, bẹ́ẹ̀ náà ni a óo torí ìgbọràn ẹnìkan dá gbogbo eniyan láre. Ọ̀nà ẹ̀bùrú ni òfin gbà wọlé, kí ẹ̀ṣẹ̀ lè pọ̀ jantirẹrẹ. Níbi tí ẹ̀ṣẹ̀ bá sì ti pọ̀, oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun a máa pọ̀ ju bí ẹ̀ṣẹ̀ ti pọ̀ tó lọ. Nípa bẹ́ẹ̀, bí ikú ṣe sọ ẹ̀ṣẹ̀ di ọba, bẹ́ẹ̀ ni ìdáláre náà ń fi oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun jọba, ó sì mú wa wọnú ìyè ainipẹkun nípasẹ̀ Jesu Kristi Oluwa wa. Kí ni kí á wí nígbà náà? Ṣé kí a túbọ̀ máa dẹ́ṣẹ̀ kí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun lè máa pọ̀ sí i? Kí á má rí i. Báwo ni àwa tí a ti fi ayé ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀, ṣe tún lè máa gbé inú ẹ̀ṣẹ̀? Àbí ẹ kò mọ̀ pé gbogbo àwa tí a ti rì bọmi lórúkọ Jesu a ti kú bí Jesu ti kú? Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n jọ sin wá pọ̀ nígbà tí wọ́n rì wá bọmi, tí wọ́n sọ wá di òkú, kí àwa náà lè máa gbé ìgbé-ayé titun gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun baba ògo ti jí Kristi dìde kúrò ninu òkú. Bí a bá sọ wá di ọ̀kan náà pẹlu Jesu ninu ikú, a óo sọ wá di ọ̀kan náà pẹlu rẹ̀ ninu ajinde. Ẹ jẹ́ kí òye yìí yé wa: a ti kan ẹni àtijọ́ tí àwọn eniyan mọ̀ wá sí mọ́ agbelebu pẹlu Jesu, kí ẹran-ara tí eniyan fi ń dẹ́ṣẹ̀ lè di òkú, kí á lè bọ́ lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí ẹni tí ó ti kú ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Bí a bá jọ bá Jesu kú, a ní igbagbọ pé a óo jọ bá Jesu yè. A mọ̀ pé Kristi tí a ti jí dìde kúrò ninu òkú, kò tún ní kú mọ́; ikú kò sì lè jọ̀gá lórí rẹ̀ mọ́. Kíkú tí ó kú jẹ́ pé ó ti kú ikú tí ó níláti kú lẹ́ẹ̀kan; yíyè tí ó yè, ó yè fún ògo Ọlọrun. Bákan náà ni kí ẹ ka ara yín bí ẹni tí ó ti kú ní ayé ẹ̀ṣẹ̀, tí ó tún wà láàyè pẹlu Ọlọrun ninu Kristi. Nítorí èyí, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ tún rí ààyè jọba ninu ara yín tí ẹ óo fi máa fààyè fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara. Ẹ má sì gbé ara yín sílẹ̀ bí ohun èèlò fún ẹ̀ṣẹ̀. Dípò èyí, ẹ lo ara yín fún iṣẹ́ òdodo, kí ẹ sì fi í fún Ọlọrun, ẹni tí ó lè sọ òkú dààyè. Ẹ má jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ di ọ̀gá yín, nítorí ẹ kò sí lábẹ́ Òfin; abẹ́ oore-ọ̀fẹ́ ni ẹ wà. Kí ló wá kù kí á ṣe? Ṣé kí á máa dá ẹ̀ṣẹ̀ nítorí pé a kò sí lábẹ́ òfin, abẹ́ oore-ọ̀fẹ́ ni a wà. Ká má rí i. Ẹ kò mọ̀ pé ẹrú ẹni tí ẹ bá ń gbọ́ràn sí lẹ́nu lẹ jẹ́, ẹnikẹ́ni tí ẹ bá fara yín ṣẹrú fún, tí ẹ sì ń jíṣẹ́ fún? Ẹ lè fi ara yín ṣẹrú fún ẹ̀ṣẹ̀, kí ó fikú san án fun yín; ẹ sì lè fìgbọràn ṣọ̀gá fún ara yín, kí ó sì fun yín ní ìdáláre. Ọpẹ́ ni fỌlọrun, nítorí pé ẹ̀yin tí ẹ̀ ń ṣẹrú ẹ̀ṣẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí, ti wá ń fi tọkàntọkàn gba irú ẹ̀kọ́ tí a gbé kalẹ̀ níwájú yín. A ti tu yín sílẹ̀ ninu ọgbà ẹ̀wọ̀n ẹ̀ṣẹ̀, ẹ ti di ẹrú iṣẹ́ rere. Mò ń fọ èdè tí ó lè yé eniyan, nítorí ọgbọ́n yín kò ì tíì kọjá ohun tí a lè fi ojú rí. Bí ẹ ti gbé ara yín fún ìwà èérí ati ìwà tinú-mi-ni-n-óo-ṣe, tí a sì fi yín sílẹ̀ kí ẹ máa ṣe bí ó ti wù yín, bẹ́ẹ̀ náà ni kí ẹ wá fi ara yín jìn fún iṣẹ́ rere, kí ẹ sìn ín fún iṣẹ́ mímọ́. Nígbà tí ẹ jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, kò sí ohun tí ẹ bá iṣẹ́ rere dàpọ̀. Èrè wo ni ẹ rí gbà lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, àfi ohun tí ń tì yín lójú nisinsinyii? Ikú ni irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ máa ń yọrí sí. Ṣugbọn nisinsinyii tí ẹ ti bọ́ lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, tí ẹ ti di ẹrú Ọlọrun, èrè tí ẹ óo máa rí, ti ohun mímọ́ ni. Ìyè ainipẹkun ni yóo sì yọrí sí. Ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀, ṣugbọn ẹ̀bùn Ọlọrun ni ìyè ainipẹkun pẹlu Jesu Kristi Oluwa wa. Ẹ̀yin ará mi, ohun tí mò ń wí yìí kò ṣe àjèjì si yín (nítorí ẹ̀yin náà mọ òfin), pé òfin de eniyan níwọ̀n ìgbà tí ó bá wà láàyè nìkan. Bí àpẹẹrẹ, òfin igbeyawo de abilekọ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ rẹ̀ wà láàyè. Ṣugbọn bí ọkọ rẹ̀ bá kú, òfin tí ó de obinrin náà mọ́ ọkọ rẹ̀ kò ṣiṣẹ́ mọ́. Wàyí ò, bí obinrin náà bá lọ bá ọkunrin mìíràn nígbà tí ọkọ rẹ̀ wà láàyè, alágbèrè ni a óo pè é. Ṣugbọn tí ọkọ rẹ̀ bá ti kú, ó bọ́ lọ́wọ́ òfin igbeyawo, kì í ṣe àgbèrè mọ́, bí ó bá lọ fẹ́ ọkọ mìíràn. Bẹ́ẹ̀ náà ni, ẹ̀yin ará mi, ẹ̀yin náà ti kú ní ti Òfin, nígbà tí ẹ di ara kan náà pẹlu Kristi. Ẹ ti ní ọkọ mìíràn, àní, ẹni tí a ti jí dìde kúrò ninu òkú, kí á lè sin Ọlọrun lọ́nà tí yóo yọrí sí rere. Tẹ́lẹ̀ rí, nígbà tí a ti ń ṣe ìfẹ́ inú wa bí ẹlẹ́ran-ara, èrò ọkàn wa a máa fà sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Òfin dá wa lẹ́kun rẹ̀, láti tì wá sí ohun tí àyọrísí rẹ̀ jẹ́ ikú. Ṣugbọn nisinsinyii, a ti bọ́ kúrò lábẹ́ Òfin. A ti kú sí ohun tí ó dè wá. Báyìí, a kò sin Ọlọrun lọ́nà àtijọ́ mọ́, àní lọ́nà ti Òfin àkọsílẹ̀, ṣugbọn ní ọ̀nà titun ti Ẹ̀mí. Kí ni kí á wá wí wàyí ò? Ṣé Òfin wá jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ni? Rárá o! Ṣugbọn ṣá, èmi kì bá tí mọ ẹ̀ṣẹ̀ bí Òfin kò bá fi í hàn mí. Bí àpẹẹrẹ, ǹ bá tí mọ ojúkòkòrò bí Òfin kò bá sọ pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò.” Àṣẹ yìí ni ẹ̀ṣẹ̀ rí dìrọ̀ mọ́ láti fi ṣiṣẹ́. Ó ń fi èrò oríṣìíríṣìí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí mi lọ́kàn. Bí a bá mú òfin kúrò, ẹ̀ṣẹ̀ di òkú. Nígbà kan rí mò ń gbé ìgbésí-ayé mi láìsí òfin. Ṣugbọn nígbà tí òfin dé, ẹ̀ṣẹ̀ yọjú pẹlu, ni mo bá kú. Òfin tí ó yẹ kí ó mú ìyè wá, ni ó wá di ọ̀ràn ikú fún mi. Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ rí ohun dìrọ̀ mọ́ ninu òfin, ó tàn mí jẹ, ó sì pa mí kú. Dájú, ohun mímọ́ ni Òfin, àwọn àṣẹ tí ó wà ninu rẹ̀ náà sì jẹ́ ohun mímọ́, ohun tí ó tọ́, tí ó sì dára. Ǹjẹ́ ohun tí ó dára yìí ni ó ṣe ikú pa mí? Rárá o! Ẹ̀ṣẹ̀ níí ṣekú pani. Kí ẹ̀ṣẹ̀ lè fara rẹ̀ hàn bí ẹ̀ṣẹ̀, ó lo ohun tí ó dára láti pa mí kú, báyìí, ó hàn gbangba pé ibi gan-an ni ẹ̀ṣẹ̀ í ṣe, nítorí ó kó sábẹ́ òfin láti ṣe ibi. Àwa mọ̀ dájú pé Òfin jẹ́ nǹkan ti Ẹ̀mí. Ṣugbọn èmi jẹ́ eniyan ẹlẹ́ran-ara, tí a ti tà lẹ́rú fún ẹ̀ṣẹ̀. Ìwà mi kò yé èmi alára; nítorí kì í ṣe àwọn nǹkan tí mo bá fẹ́ ṣe ni mò ń ṣe, àwọn nǹkan tí mo kórìíra gan-an ni mò ń ṣe. Níwọ̀n ìgbà tí mo bá ń ṣe àwọn nǹkan tí n kò fẹ́, mò ń jẹ́rìí sí i pé Òfin jẹ́ ohun tí ó dára. Wàyí ò, ó já sí pé kì í ṣe èmi alára ni mò ń hùwà bẹ́ẹ̀, bíkòṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ń gbé inú mi. Mo mọ̀ dájú pé, kò sí agbára kan ninu èmi eniyan ẹlẹ́ran-ara, láti ṣe rere, n kò lágbára láti ṣe é. Nítorí kì í ṣe nǹkan rere tí mo fẹ́ ṣe ni mò ń ṣe, ṣugbọn àwọn nǹkan burúkú tí n kò fẹ́, ni mò ń ṣe. Tí ó bá wá jẹ́ pé àwọn nǹkan tí n kò fẹ́ ni mò ń ṣe, a jẹ́ pé kì í ṣe èmi ni mò ń ṣe é, bíkòṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ń gbé inú mi. Mo wá rí i wàyí pé, ó ti di bárakú fún mi, pé nígbà tí mo bá fẹ́ ṣe rere, àwọn nǹkan burúkú ni ó yá sí mi lọ́wọ́. Mo yọ̀ gidigidi ninu ọkàn mi pé Ọlọrun ṣe òfin. Ṣugbọn bí mo ti wòye, àwọn ẹ̀yà ara mi ń tọ ọ̀nà mìíràn, tí ó lòdì sí ọ̀nà tí ọkàn mi fẹ́, ọ̀nà òdì yìí ni ó gbé mi sinu ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ninu àwọn ẹ̀yà ara mi. Irú ẹ̀dá wo tilẹ̀ ni tèmi yìí! Ta ni yóo gbà mí lọ́wọ́ ara tí ó fẹ́ ṣekú pa mí yìí? Háà! Ọpẹ́ ni fún Ọlọrun! Òun nìkan ló lè gbà mí là nípa Jesu Kristi Oluwa wa. Bí ọ̀rọ̀ ara mi ti wá rí nìyí: ní ìdà kinni, mò ń tẹ̀lé ìlànà òfin Ọlọrun ninu àwọn èrò ọkàn mi: ní ìdà keji ẹ̀wẹ̀, èmi yìí kan náà, gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ran-ara, mo tún ń tọ ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀. Nisinsinyii, kò sí ìdálẹ́bi kan mọ́ fún àwọn tí ó wà ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi Jesu. Ìdí ni pé, agbára Ẹ̀mí, tí ó ń fi ìyè fún àwọn tí ń bá Kristi gbé, ti dá mi nídè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ati kúrò lábẹ́ àṣẹ ikú. Èyí jẹ́ nǹkan tí kò ṣe é ṣe lábẹ́ Òfin, nítorí eniyan kò lè ṣàì dẹ́ṣẹ̀. Ṣugbọn Ọlọrun ti ṣe é, nígbà tí ó dá ẹ̀bi ikú fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ninu ẹ̀yà ara eniyan. Àní sẹ́, Ọlọrun rán Ọmọ rẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí eniyan ẹlẹ́ṣẹ̀ láti pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́. Ọlọrun ṣe èyí kí á lè tẹ̀lé ìlànà Òfin ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, àní àwa tí ìhùwàsí wa kì í ṣe bíi tí ẹni tí ẹran-ara ń lò ṣugbọn bí àwọn ẹni tí Ẹ̀mí ń darí. Nítorí àwọn tí ó ń hùwà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ẹran- ara ń lò a máa lépa ìtẹ́lọ́rùn fún ẹran-ara; ṣugbọn àwọn tí Ẹ̀mí ń darí a máa lépa àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí. Lílépa àwọn nǹkan ti ẹran-ara nìkan a máa yọrí sí ikú, ṣugbọn lílépa àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí a máa fúnni ní ìyè ati alaafia. Ìdí nìyí tí àwọn tí ń lépa nǹkan ti ẹran-ara nìkan fi jẹ́ ọ̀tá Ọlọrun, nítorí àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò lè fara wọn sábẹ́ àṣẹ Ọlọrun; wọn kò tilẹ̀ lè ṣe é rárá ni. Àwọn tí ń ṣe ìfẹ́ ẹran-ara wọn kò lè sin Ọlọrun. Ṣugbọn ní tiyín, ẹ kò hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ẹran-ara ń darí mọ́; Ẹ̀mí ló ń ṣamọ̀nà yín, bí Ẹ̀mí Ọlọrun bá ń gbé inú yín nítòótọ́. Nítorí pé ẹnikẹ́ni tí kò bá ní Ẹ̀mí Kristi ninu rẹ̀, kì í ṣe ti Kristi. Ṣugbọn bí Kristi bá ń gbé inú yín, bí ara yín yóo tilẹ̀ kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀, sibẹ ẹ̀mí yín yóo wà láàyè nítorí pé Ọlọrun ti da yín láre. Ǹjẹ́ bí Ẹ̀mí Ọlọrun, ẹni tí ó jí Jesu dìde kúrò ninu òkú, bá ń gbé inú yín, òun náà tí ó jí Kristi dìde kúrò ninu òkú yóo sọ ara yín, tí yóo kú, di alààyè nípa Ẹ̀mí rẹ̀, tí ó ń gbé inú yín. Nítorí náà, ẹ̀yin ará, kò sí ohunkohun mọ́ tí ó mú wa ní túlààsì pé kí á máa hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ẹran-ara ń darí. Nítorí bí ẹ bá hùwà bí àwọn tí ẹran-ara ń darí, kíkú ni ẹ óo kú dandan. Ṣugbọn tí ẹ bá ń rìn lọ́nà ti Ẹ̀mí, tí ẹ kò sì hu ìwà ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, ẹ óo yè. Nítorí àwọn tí Ẹ̀mí Ọlọrun bá ń darí ni ọmọ Ọlọrun. Ẹ̀mí tí Ọlọrun fun yín kì í ṣe èyí tí yóo tún sọ yín di ẹrú, tí yóo sì máa mu yín bẹ̀rù. Ṣugbọn Ẹ̀mí tí ó sọ yín di ọmọ ni ẹ gbà. Ẹ̀mí yìí náà ni ó jẹ́ kí á lè máa ké pe Ọlọrun pé, “Baba! Baba wa!” Ẹ̀mí kan náà ní ń sọ sí wa lọ́kàn pé ọmọ Ọlọrun ni wá. Wàyí ò, tí a bá jẹ́ ọmọ, ajogún ni wá. Tí a bá sì jẹ́ ajogún, a jẹ́ pé àwa pẹlu Kristi ni a óo jọ jogún pọ̀, bí a bá bá Kristi jìyà, a óo bá a gba iyì pẹlu. Mo wòye pé a kò lè fi ìyà ayé yìí wé ọlá tí Ọlọrun yóo dá wa ní ayé tí ń bọ̀ wá. Nítorí gbogbo ẹ̀dá ayé ló ń fi ìwàǹwára nàgà, tí wọn ń retí àkókò tí Ọlọrun yóo fi àwọn tíí ṣe ọmọ rẹ̀ hàn. Nítorí pé gbogbo ẹ̀dá ayé ló ti pasán, kì í ṣe pé ẹ̀dá ayé fúnra wọn ni wọ́n fẹ́ pasán, ṣugbọn bẹ́ẹ̀ ni ó wu Ẹlẹ́dàá láti yàn án. Sibẹ ìrètí ń bẹ pé: ẹ̀dá ayé pàápàá yóo bọ́ lóko ẹrú, kúrò ninu ipò ìdíbàjẹ́, yóo sì pín ninu ọlá àwọn ọmọ Ọlọrun. Àwa náà rí i pé, títí di òní olónìí, gbogbo ẹ̀dá ayé ni wọ́n ń jẹ̀rora, tí wọ́n sì ń rọbí bí aboyún. Ṣugbọn kì í ṣe ẹ̀dá ayé nìkan ló ń jẹ̀rora. Àní sẹ́, àwa fúnra wa, tí a ti rí Ẹ̀mí Ọlọrun gbà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn rẹ̀ àkọ́kọ́, à ń jẹ̀rora lọ́kàn wa, bí a ti ń retí àkókò tí Ọlọrun yóo pè wá lọ́mọ rẹ̀, tí yóo sì dá gbogbo ara wa nídè. Nítorí ti ìrètí yìí ni a fi gbà wá là. Ṣebí ohun tí a bá ti fojú rí ti kúrò ní ohun tí à ń retí. Àbí, ta ni í tún máa ń retí ohun tí ó bá ti rí? Ṣugbọn nígbà tí a bá ń retí ohun tí a kò ì tíì fojú rí, dídúró ni à á dúró dè é pẹlu ìfaradà títí yóo fi tẹ̀ wá lọ́wọ́. Bákan náà, Ẹ̀mí tún ń ràn wá lọ́wọ́ ninu àìlera wa. Nítorí a kò mọ ohun tí ó tọ́ tí à bá máa gbadura fún. Ṣugbọn Ẹ̀mí fúnrarẹ̀ a máa bẹ̀bẹ̀ fún wa lọ́dọ̀ Ọlọrun lọ́nà tí a kò lè fi ẹnu sọ. Ọlọrun, Olùmọ̀ràn ọkàn, mọ èrò tí ó wà lọ́kàn Ẹ̀mí, nítorí Ẹ̀mí níí máa bẹ̀bẹ̀ fún àwọn eniyan Ọlọrun bí Ọlọrun fúnrarẹ̀ ti fẹ́. Àwa mọ̀ dájú pé Ọlọrun a máa mú kí ohun gbogbo yọrí sí rere fún àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ̀, àwọn tí ó ti pè gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ̀ láti ayébáyé. Nítorí àwọn tí Ọlọrun ti yàn tẹ́lẹ̀, àwọn ni ó yà sọ́tọ̀ kí wọ́n lè dàbí Ọmọ rẹ̀, kí Ọmọ rẹ̀ yìí lè jẹ́ àkọ́bí láàrin ọpọlọpọ mọ̀lẹ́bí. Àwọn tí Ọlọrun ti yàn tẹ́lẹ̀, àwọn ni ó pè. Àwọn tí ó pè ni ó dá láre. Àwọn tí ó sì dá láre ni ó dá lọ́lá. Kí ni kí á wá wí sí gbogbo nǹkan wọnyi? Bí Ọlọrun bá wà lẹ́yìn wa, ta ni lè lòdì sí wa? Ọlọrun, tí kò dá Ọmọ rẹ̀ sí, ṣugbọn tí ó yọ̀ǹda rẹ̀ nítorí gbogbo wa, báwo ni kò ṣe ní fún wa ní ohun gbogbo pẹlu rẹ̀? Ta ni yóo fi ẹ̀sùn kan kan àwọn ẹni tí Ọlọrun ti yàn? Ṣé Ọlọrun ni, òun tí ó dá wọn láre? Àbí ta ni yóo dá wọn lẹ́bi? Dájúdájú, kò lè jẹ́ Kristi, ẹni tí ó kú, àní sẹ́ ẹni tí a jí dìde kúrò ninu òkú, tí ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun, tí ó sì ń bẹ̀bẹ̀ fún wa. Ta ni yóo yà wá kúrò ninu ìfẹ́ Kristi? Ìpọ́njú ni bí, tabi ìṣòro, tabi inúnibíni, tabi ìyàn, tabi òṣì, tabi ewu, tabi idà? Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Nítorí rẹ a wà ninu ewu ikú lojoojumọ, wọ́n sì ṣe wá bí aguntan tí wọ́n fẹ́ lọ pa.” Ṣugbọn ninu gbogbo ìrírí wọnyi, a ti borí gbogbo ìṣòro nípa agbára ẹni tí ó fẹ́ràn wa. Nítorí ó dá mi lójú pé, kò sí ohunkohun–ìbáà ṣe ikú tabi ìyè, ìbáà ṣe àwọn angẹli tabi àwọn irúnmọlẹ̀, tabi àwọn ohun ayé òde òní tabi àwọn ti ayé tí ó ń bọ̀, yálà àwọn àlùjọ̀nnú ojú-ọ̀run tabi àwọn ẹbọra inú ilẹ̀; lọ́rọ̀ kan, kò sí ẹ̀dá náà tí ó lè yà wá kúrò ninu ìfẹ́ tí Ọlọrun ní sí wa nípasẹ̀ Kristi Jesu Oluwa wa. Òtítọ́ ni ohun tí mò ń sọ yìí; n kò purọ́, nítorí Kristi ni ó ni mí. Ọkàn mi tí Ẹ̀mí ń darí sì jẹ́ mi lẹ́rìí pẹlu, pé, ohun ìbànújẹ́ ńlá ati ẹ̀dùn ọkàn ni ọ̀ràn àwọn eniyan mi jẹ́ fún mi nígbà gbogbo. Mo fẹ́rẹ̀ lè gbadura pé kí á sọ èmi fúnra mi di ẹni ègún, kí á yà mí nípa kúrò lọ́dọ̀ Kristi nítorí ti àwọn ará mi, àwọn tí a jọ jẹ́ ẹ̀yà kan náà. Ọmọ Israẹli ni wọ́n. Àwọn ni Ọlọrun yàn bí ọmọ rẹ̀. Àwọn ni ó fi ògo rẹ̀ hàn fún. Àwọn náà ni ó bá dá majẹmu, tí ó fún ní Òfin rẹ̀, tí ó sì kọ́ lọ́nà ẹ̀sìn rẹ̀. Àwọn ni ó ṣe ìlérí fún. Àwọn ni irú-ọmọ àwọn baba-ńlá ayé àtijọ́. Láàrin wọn ni Mesaya sì ti wá sáyé gẹ́gẹ́ bí eniyan. Ìyìn ni fún Ọlọrun, ẹni tíí ṣe olùdarí ohun gbogbo, lae ati laelae. Amin. Sibẹ, kì í ṣe pé ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti kùnà patapata. Nítorí kì í ṣe gbogbo àwọn tí a bí sinu ìdílé Israẹli ni ọmọ Israẹli tòótọ́. Kì í ṣe gbogbo àwọn tí ó jẹ́ ìran Abrahamu ni ọmọ rẹ̀ tòótọ́, nítorí bí Ìwé Mímọ́ ti wí, Ọlọrun sọ fún Abrahamu pé, “Àwọn ọmọ Isaaki nìkan ni a óo kà sí ìran fún ọ.” Èyí ni pé, kì í ṣe àwọn ọmọ tí a bí nípa ti ara lásán ni ọmọ Ọlọrun. Àwọn ọmọ tí a bí nípa ìlérí Ọlọrun ni a kà sí ìran Abrahamu. Nítorí báyìí ni ọ̀rọ̀ ìlérí náà: “Nígbà tí mo bá pada wá ní ìwòyí àmọ́dún, Sara yóo ti bí ọmọkunrin kan.” Èyí nìkan kọ́. Rebeka bímọ meji fún ẹnìkan ṣoṣo, òun náà ni baba wa Isaaki. Ṣugbọn kí á tó bí àwọn ọmọ náà, àní sẹ́, kí wọ́n tó dá ohunkohun ṣe, yálà rere ni tabi burúkú, ni Ọlọrun ti sọ fún Rebeka pé, “Èyí ẹ̀gbọ́n ni yóo máa ṣe iranṣẹ àbúrò rẹ̀.” Báyìí ni Ọlọrun ti ń ṣe ìpinnu rẹ̀ láti ayébáyé, nígbà tí ó bá yan àwọn kan. Ó wá hàn kedere pé Ọlọrun kì í wo iṣẹ́ ọwọ́ eniyan kí ó tó yàn wọ́n; àwọn tí ó bá pinnu tẹ́lẹ̀ láti yàn ní í pè. *** Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Jakọbu ni mo yàn, Esau ni mo kọ̀.” Kí ni kí á wá wí sí èyí? Kí á wí pé Ọlọrun ń ṣe àìdára ni bí? Rárá o! Nítorí ó sọ fún Mose pé, “Ẹni tí mo bá fẹ́ ṣàánú ni n óo ṣàánú; ẹni tí mo bá sì fẹ́ yọ́nú sí ni n óo yọ́nú sí.” Nítorí náà, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí eniyan ti fẹ́ tabi bí ó ti gbìyànjú tó ni Ọlọrun fi ń yàn án, bí ó bá ti wu Ọlọrun ninu àánú rẹ̀ ni. Nítorí Ọlọrun sọ ninu Ìwé Mímọ́ nípa Farao pé, “Ìdí tí mo fi fi ọ́ jọba ni pé, mo fẹ́ fi ọ́ ṣe àpẹẹrẹ bí agbára mi ti tó, ati pé kì ìròyìn orúkọ mi lè tàn ká gbogbo ayé.” Nítorí náà, ẹni tí ó bá wu Ọlọrun láti ṣàánú, a ṣàánú rẹ̀, ẹni tí ó bá sì wù ú láti dí lọ́kàn, a dí i lọ́kàn. Wàyí, ẹnìkan lè sọ fún mi pé, “Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló dé tí Ọlọrun fi ń bá eniyan wí? Ta ni ó tó takò ó pé kí ó má ṣe ohun tí ó bá wù ú?” Ṣugbọn ta ni ọ́, ìwọ ọmọ-eniyan, tí o fi ń gbó Ọlọrun lẹ́nu? Ǹjẹ́ ìkòkò lè wí fún ẹni tí ó ń mọ ọ́n pé, “Kí ló dé tí o fi ṣe mí báyìí?” Àbí amọ̀kòkò kò ní ẹ̀tọ́ láti ṣe amọ̀ rẹ̀ bí ó ti wù ú bí? Bí ó bá fẹ́, ó lè fi amọ̀ rẹ̀ mọ ìkòkò tí ó wà fún èèlò ọ̀ṣọ́. Bí ó bá sì tún fẹ́, ó lè mú lára amọ̀ kan náà kí ó fi mọ ìkòkò mìíràn fún èèlò lásán. Bẹ́ẹ̀ náà ni ohun tí Ọlọrun ṣe rí. Ó wù ú láti fi ibinu ati agbára rẹ̀ hàn. Ó wá fi ọ̀pọ̀ sùúrù fara da àwọn tí ó yẹ kí ó fi ibinu parun. Báyìí náà ni ó fi ògo ńlá rẹ̀ hàn pẹlu fún àwọn tí ó ṣàánú fún, àní fún àwa tí ó ti pèsè ọlá sílẹ̀ fún. Àwa náà ni ó pè láti ààrin àwọn Juu ati láti ààrin àwọn tí kìí ṣe Juu pẹlu; bí ó ti sọ ninu Ìwé Hosia pé, “Èmi yóo pe àwọn tí kì í ṣe eniyan mi ní ‘Eniyan mi.’ N óo sì pe àwọn orílẹ̀-èdè tí n kò náání ní ‘Àyànfẹ́ mi.’ Ní ibìkan náà tí a ti sọ fún wọn rí pé, ‘Ẹ kì í ṣe eniyan mi mọ́’ ni a óo ti pè wọ́n ní ọmọ Ọlọrun alààyè.” Aisaya náà kéde nípa Israẹli pé, “Bí àwọn ọmọ Israẹli tilẹ̀ pọ̀ bí iyanrìn òkun, sibẹ díẹ̀ péré ni a óo gbà là. Nítorí ṣókí ati wéré wéré ni ìdájọ́ Ọlọrun yóo jẹ́ lórí ilẹ̀ ayé.” Ṣiwaju eléyìí, Aisaya sọ bákan náà pé, “Bíkòṣe pé Oluwa alágbára jùlọ dá díẹ̀ sí ninu àwọn ọmọ wa ni, bíi Sodomu ni à bá rí, à bá sì dàbí Gomora.” Kí ni èyí já sí? Ó já sí pé àwọn orílẹ̀-èdè tí kò bìkítà rárá láti wá ojurere Ọlọrun, àwọn náà gan-an ni Ọlọrun wá dá láre, ó dá wọn láre nítorí wọ́n gbàgbọ́; ṣugbọn Israẹli tí ó ń lépa òfin tí yóo mú wọn rí ìdáláre gbà níwájú Ọlọrun kò rí irú òfin bẹ́ẹ̀. Nítorí kí ni wọn kò ṣe rí òfin náà? Ìdí ni pé, wọn kò wá ìdáláre níwájú Ọlọrun nípa igbagbọ, ṣugbọn wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Wọ́n bá kọsẹ̀ lórí òkúta ìkọsẹ̀, bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Mo gbé òkúta kan kalẹ̀ ní Sioni tí yóo mú eniyan kọsẹ̀, tí yóo gbé eniyan ṣubú. Ṣugbọn ojú kò ní ti ẹni tí ó bá gbà á gbọ́.” Ẹ̀yin ará mi, ìfẹ́ ọkàn mi, ati ẹ̀bẹ̀ mi sí Ọlọrun fún àwọn Juu, àwọn eniyan mi ni pé kí á gbà wọ́n là. Nítorí mo jẹ́rìí wọn pé wọ́n ní ìtara láti sin Ọlọrun, ṣugbọn wọn kò ní òye bí ó ti yẹ kí wọ́n sìn ín. Wọn kò tíì ní òye ọ̀nà tí Ọlọrun fi ń dáni láre, nítorí náà wọ́n wá ọ̀nà ti ara wọn, wọn kò sì fi ara wọn sábẹ́ ètò tí Ọlọrun ṣe fún ìdániláre. Nítorí Kristi ti fi òpin sí Òfin láti mú gbogbo ẹni tí ó bá gbàgbọ́ rí ìdáláre níwájú Ọlọrun. Mose kọ sílẹ̀ báyìí nípa ìdáláre tí Òfin lè fúnni pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa wọ́n mọ́, yóo ti ipa wọn rí ìyè.” Ṣugbọn báyìí ni Ìwé Mímọ́ wí nípa ìdáláre tí à ń gbà nípa igbagbọ, pé, “Má ṣe wí ní ọkàn rẹ pé, ‘Ta ni yóo gòkè lọ sọ́run?’ ” (Èyí ni láti mú Kristi sọ̀kalẹ̀.) “Tabi, ‘Ta ni yóo wọ inú ọ̀gbun ilẹ̀ lọ?’ ” (Èyí ni, láti mú Kristi jáde kúrò láàrin àwọn òkú.) Ṣugbọn ohun tí ó sọ ni pé, “Ọ̀rọ̀ náà wà nítòsí rẹ, àní, ó wà lẹ́nu rẹ ati lọ́kàn rẹ.” Èyí ni ọ̀rọ̀ igbagbọ tí à ń waasu, pé: bí ìwọ bá fi ẹnu rẹ jẹ́wọ́ pé, “Jesu ni Oluwa,” tí o sì gbàgbọ́ lọ́kàn rẹ pé Ọlọrun jí i dìde kúrò ninu òkú, a óo gbà ọ́ là. Nítorí pẹlu ọkàn ni a fi ń gbàgbọ́ láti rí ìdáláre gbà. Ṣugbọn ẹnu ni a fi ń jẹ́wọ́ láti rí ìgbàlà. Ìwé Mímọ́ sọ pé, “Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́ tí ojú yóo tì.” Nítorí kò sí ìyàtọ̀ kan láàrin Juu ati Giriki. Nítorí Ọlọrun kan náà ni Oluwa gbogbo wọn, ọlá rẹ̀ sì pọ̀ tó fún gbogbo àwọn tí ó bá ń ké pè é. Gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ké pe orúkọ Oluwa ni a óo gbà là.” Ṣugbọn báwo ni wọn yóo ṣe ké pe ẹni tí wọn kò gbàgbọ́? Báwo ni wọn yóo ṣe gba ẹni tí wọn kò gbúròó rẹ̀ gbọ́? Báwo ni wọn yóo ṣe gbúròó rẹ̀ láìsí àwọn tí ó ń kéde rẹ̀? Báwo ni àwọn kan yóo ṣe lọ kéde rẹ̀ láìjẹ́ pé a bá rán wọn lọ? Ó wà ninu Ìwé Mímọ́ pé, “Àwọn tí ó mú ìyìn rere wá mà mọ̀ ọ́n rìn o!” Ṣugbọn kì í ṣe gbogbo wọn ni ó gba ìyìn rere yìí gbọ́. Aisaya ṣá sọ ọ́ pé, “Oluwa, ta ni ó gba ohun tí a sọ gbọ́?” Ṣebí ohun tí a bá gbọ́ ni à ń gbàgbọ́, ohun tí a sì gbọ́ yìí ni ọ̀rọ̀ Kristi? Mo wá ń bèèrè, “Ṣé wọn kò ì tíì gbọ́ ni?” Wọ́n kúkú ti gbọ́, nítorí a rí i kà ninu Ìwé Mímọ́ pé, “Ìró wọn ti dé gbogbo orílẹ̀-èdè, àní, ọ̀rọ̀ wọn ti dé òpin ayé.” Mo tún bèèrè: Àbí Israẹli kò mọ̀ ni? Ẹ jẹ́ kí á gbọ́ ohun tí Mose kọ́kọ́ sọ; ó ní, “N óo jẹ́ kí àwọn tí kì í ṣe orílẹ̀-èdè mu yín jowú, N óo sì jẹ́ kí orílẹ̀-èdè tí kò lóye mú kí ara ta yín.” Aisaya pàápàá kò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ kọ́ òun lẹ́nu, ó ní, “Àwọn tí kò wá mi ni wọ́n rí mi, àwọn tí kò bèèrè mi ni mo fi ara hàn fún.” Ṣugbọn ohun tí ó ní Ọlọrun wí fún Israẹli ni pé, “Láti òwúrọ̀ títí di alẹ́ ni mo na ọwọ́ mi sí àwọn aláìgbọràn ati alágídí eniyan.” Ǹjẹ́, mo bèèrè: ṣé Ọlọrun ti wá kọ àwọn eniyan rẹ̀ sílẹ̀ ni? Rárá o! Ọmọ Israẹli ni èmi fúnra mi. Ìran Abrahamu ni mí, láti inú ẹ̀yà àwọn ọmọ Bẹnjamini. Ọlọrun kò kọ àwọn eniyan rẹ̀ sílẹ̀, àwọn tí ó ti yàn láti ìpilẹ̀ṣẹ̀. Tabi ẹ kò mọ ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ ninu ìtàn Elija? Ó ní, “Oluwa, wọ́n ti pa àwọn wolii rẹ, wọ́n ti wó pẹpẹ ìrúbọ rẹ, èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù, wọ́n sì ń wá mi láti pa.” Ṣugbọn kí ni Ọlọrun wí fún un? Ó ní “Ẹẹdẹgbaarin (7,000) eniyan ṣì kù fún mi tí wọn kò tíì wólẹ̀ bọ Baali rí.” Bẹ́ẹ̀ náà ló rí ní àkókò yìí, àwọn kan kù tí Ọlọrun yàn nítorí oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀. Tí ó bá wá jẹ́ pé nítorí oore-ọ̀fẹ́ ni Ọlọrun fi yàn wọ́n, kò tún lè jẹ́ nítorí iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, oore-ọ̀fẹ́ kò ní jẹ́ oore-ọ̀fẹ́ mọ́. Kí wá ni? Ohun tí Israẹli ń wá kò tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́. Ṣugbọn ó tẹ àwọn díẹ̀ tí a yàn ninu wọn lọ́wọ́. Etí àwọn yòókù di sí ìpè Ọlọrun, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ọlọrun fún wọn ní iyè tí ó ra, ojú tí kò ríran, ati etí tí kò gbọ́ràn títí di òní olónìí.” Dafidi náà sọ pé, “Jẹ́ kí àsè wọn di tàkúté ati àwọ̀n, kí ó gbé wọn ṣubú, kí ó mú ẹ̀san bá wọn. Jẹ́ kí ojú wọn ṣókùnkùn, kí wọn má lè ríran. Jẹ́ kí ẹ̀yìn wọn tẹ̀, kí wọn má lè nàró mọ́.” Mo tún bèèrè: ǹjẹ́ nígbà tí àwọn Juu kọsẹ̀, ṣé wọ́n ṣubú gbé ni? Rárá o! Ṣugbọn nítorí ìṣìnà wọn ni ìgbàlà fi dé ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, kí àwọn Juu baà lè máa jowú. Ǹjẹ́ bí ìṣìnà wọn bá ṣe ayé ní anfaani, bí ìkùnà wọn bá ṣe orílẹ̀-èdè yòókù ní anfaani, báwo ni anfaani náà yóo ti pọ̀ tó nígbà tí gbogbo wọn bá ṣe ojúṣe wọn? Ẹ̀yin ará, tí ẹ kì í ṣe Juu ni mò ń bá sọ̀rọ̀ nisinsinyii. Níwọ̀n ìgbà tí mo jẹ́ Aposteli láàrin yín, mò ń ṣe àpọ́nlé iṣẹ́ mi, pé bóyá mo lè ti ipa bẹ́ẹ̀ mú àwọn eniyan mi jowú yín, kí n lè gba díẹ̀ ninu wọn là. Nítorí bí kíkọ̀ tí Ọlọrun kọ̀ wọ́n sílẹ̀ bá mú kí aráyé bá Ọlọrun rẹ́, kí ni yóo ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ọlọrun bá gbà wọ́n mọ́ra? Ǹjẹ́ òkú pàápàá kò ní jí dìde? Bí a bá ya ìyẹ̀fun tí a kọ́kọ́ rí ninu ìkórè sí mímọ́, a ti ya burẹdi tí a fi ṣe sí mímọ́. Bí a bá ya gbòǹgbò igi sí mímọ́, a ti ya àwọn ẹ̀ka igi náà sí mímọ́. A gé díẹ̀ ninu àwọn ẹ̀ka igi olifi inú oko kúrò, a wá lọ́ ẹ̀ka igi olifi inú tí ó lalẹ̀ hù ninu ìgbẹ́ dípò rẹ̀. Ẹ̀yin, tí ẹ kì í ṣe Juu, wá dàbí ẹ̀ka igi olifi tí ó lalẹ̀ hù ninu ìgbẹ́. Ẹ wá jọ ń rí oúnjẹ ati agbára láti ibìkan náà pẹlu àwọn Juu, tí ó jẹ́ igi olifi inú oko. Nítorí náà, má ṣe fọ́nnu bí ẹni pé o sàn ju àwọn ẹ̀ka ti àkọ́kọ́ lọ. Tí o bá ń fọ́nnu, ranti pé kì í ṣe ìwọ ni ò ń gbé gbòǹgbò ró. Ìwọ yóo wá wí pé, “Gígé ni a gé àwọn ẹ̀ka kúrò kí á lè fi mí rọ́pò wọn.” Lóòótọ́ ni. A gé wọn kúrò nítorí wọn kò gbàgbọ́, nípa igbagbọ ni ìwọ náà fi wà ní ipò rẹ. Mú èrò ìgbéraga kúrò lọ́kàn rẹ, kí o sì ní ọkàn ìbẹ̀rù. Nítorí bí Ọlọrun kò bá dá àwọn tí ó jẹ́ bí ẹ̀ka igi láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ sí, kò ní dá ìwọ náà sí. Nítorí náà ṣe akiyesi ìyọ́nú Ọlọrun ati ìrorò rẹ̀. Ó rorò sí àwọn tí ó kùnà. Yóo yọ́nú sí ọ, tí o bá farabalẹ̀ gba ìyọ́nú rẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, yóo gé ìwọ náà kúrò pẹlu. Àwọn Juu tí a gé kúrò yóo tún bọ́ sí ipò wọn pada, bí wọn bá kọ ọ̀nà aigbagbọ sílẹ̀. Ọlọrun lágbára láti tún lọ́ wọn pada sí ibi tí ó ti gé wọn. Ìwọ tí ó jẹ́ bí ẹ̀ka igi olifi tí ó la ilẹ̀ hù ninu ìgbẹ́, tí a lọ́ mọ́ ara igi olifi inú oko, tí ẹ̀dá wọn yàtọ̀ sí ara wọn, báwo ni yóo ti rọrùn tó láti tún lọ́ àwọn tí ó jẹ́ ara igi olifi inú oko tẹ́lẹ̀ mọ́ ara igi tí a ti gé wọn kúrò! Ará, mo fẹ́ kí ẹ mọ ohun àṣírí yìí, kí ẹ má baà ro ara yín jù bí ó ti yẹ lọ. Òun ni pé, apá kan ninu àwọn ọmọ Israẹli yóo jẹ́ alágídí ọkàn títí di ìgbà tí iye àwọn tí a yàn láti àwọn orílẹ̀-èdè yòókù yóo fi dé ọ̀dọ̀ Ọlọrun lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Lẹ́yìn náà, a óo wá gba gbogbo Israẹli là. A ti kọ ọ́ sílẹ̀ pé, “Olùdáǹdè yóo wá láti Sioni, yóo mú gbogbo ìwàkiwà kúrò ní ilé Jakọbu. Èyí ni majẹmu tí n óo bá wọn dá, lẹ́yìn tí mo bá mú ẹ̀ṣẹ̀ wọn kúrò.” Nítorí pé àwọn Juu kọ ìyìn rere, wọ́n sọ ara wọn di ọ̀tá Ọlọrun, èyí sì ṣe yín láǹfààní. Ṣugbọn níwọ̀n ìgbà tí Ọlọrun ti yàn wọ́n nítorí àwọn baba-ńlá orílẹ̀-èdè wọn, wọ́n jẹ́ àyànfẹ́ rẹ̀ sibẹ. Nítorí Ọlọrun kò jẹ́ kábàámọ̀ pé òun fún ẹnìkan ní ẹ̀bùn kí ó wá gbà á pada. Bí ẹ̀yin fúnra yín ti jẹ́ aláìgbọràn sí Ọlọrun nígbà kan rí, ṣugbọn tí ó wá ṣàánú yín nígbà tí àwọn Juu ṣàìgbọràn, bẹ́ẹ̀ gan-an ni, nisinsinyii tí ẹ̀yin náà rí àánú gbà, wọ́n di aláìgbọràn, kí àwọn náà lè rí àánú Ọlọrun gbà. Nítorí Ọlọrun ti ka gbogbo eniyan sí ẹlẹ́bi nítorí àìgbọràn wọn, kí ó lè ṣàánú fún gbogbo wọn papọ̀. Ọlà ati ọgbọ́n ati ìmọ̀ Ọlọrun mà kúkú jinlẹ̀ pupọ o! Àwámárìídìí ni ìdájọ́ rẹ̀. Iṣẹ́ rẹ̀ tayọ ohun tí ẹ̀dá lè tú wò. Ìwé Mímọ́ sọ báyìí pé: “Ta ni mọ inú Ọlọrun? Ta ni olùbádámọ̀ràn rẹ̀? Ta ni ó yá a ní ohunkohun rí tí ó níláti san án pada?” Nítorí lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ohun gbogbo wà, láti ọwọ́ rẹ̀ ni ohun gbogbo ti ń wá, nítorí tirẹ̀ sì ni ohun gbogbo ṣe wà. Tirẹ̀ ni ògo títí ayérayé. Amin. Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ̀yin ará, mo fỌlọrun aláàánú bẹ̀ yín pé kí ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ bí ẹbọ mímọ́ tí ó yẹ láti fi sin Ọlọrun. Èyí ni iṣẹ́ ìsìn tí ó yẹ yín. Ẹ má ṣe da ara yín pọ̀ mọ́ ayé yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kí ẹ para dà, kí ọkàn yín di titun, kí ẹ lè mòye ohun tí ó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọrun, tí ó dára, tí ó yẹ, tí ó sì pé. Nítorí nípa oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fún mi, mò ń sọ fún ẹnìkọ̀ọ̀kan láàrin yín pé kí ó má ṣe ro ara rẹ̀ jù bí ó ti yẹ lọ. Ṣugbọn kí olukuluku ronú níwọ̀n, kí ó máa ṣe jẹ́jẹ́, níwọ̀nba bí Ọlọrun ti pín ẹ̀bùn igbagbọ fún un. Nítorí bí a ti ní ẹ̀yà ara pupọ ninu ara kan, tí gbogbo àwọn ẹ̀yà ara wọnyi kì í sìí ṣe iṣẹ́ kan náà, bẹ́ẹ̀ gan-an ni gbogbo wa, bí á tilẹ̀ pọ̀, ara kan ni wá ninu Kristi, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa sì jẹ́ ẹ̀yà ara ẹnìkejì rẹ̀. Bí a ti ní oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pín oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kí á lò wọ́n. Bí ẹnìkan bá ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀, kí ó lò ó gẹ́gẹ́ bí igbagbọ rẹ̀ ti mọ. Bí ó bá jẹ́ ẹ̀bùn láti darí ètò ni, kí á lò ó láti darí ètò. Ẹni tí ó bá ní ẹ̀bùn ìkọ́ni, kí ó lo ẹ̀bùn rẹ̀ láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Bí ó bá ní ẹ̀bùn láti fúnni ní ọ̀rọ̀ ìwúrí, kí ó lò ó láti lé ìrẹ̀wẹ̀sì jìnnà. Ẹni tí ó bá ń ṣe ìtọrẹ àánú, kí ó ṣe é pẹlu ọkàn kan. Ẹni tí ó bá ní ẹ̀bùn láti ṣe aṣiwaju, kí ó ṣe é tọkàntọkàn. Ẹni tí ó bá ń ṣiṣẹ́ àánú, kí ó fọ̀yàyà ṣe é. Ìfẹ́ yín kò gbọdọ̀ ní ẹ̀tàn ninu. Ẹ kórìíra nǹkan burúkú. Ẹ fara mọ́ àwọn nǹkan rere. Ẹ ní ìfẹ́ láàrin ara yín bíi mọ̀lẹ́bí. Ní ti bíbu ọlá fún ara yín, ẹ máa fi ti ẹnìkejì yín ṣiwaju. Ẹ má jẹ́ kí ìtara yín rẹ̀yìn. Ẹ máa sin Oluwa tọkàntọkàn. Ẹ máa yọ̀ nítorí ìrètí tí ẹ ní. Ẹ máa fara da ìṣòro, kí ẹ sì tẹra mọ́ adura. Ẹ pín àwọn aláìní láàrin àwọn onigbagbọ ninu ohun ìní yín. Ẹ máa ṣaájò àwọn àlejò. Ẹ máa súre fún àwọn tí ó ń ṣe inúnibíni yín, kàkà kí ẹ ṣépè, ìre ni kí ẹ máa sú fún wọn. Àwọn tí ń yọ̀, ẹ bá wọn yọ̀, àwọn tí ń sunkún, ẹ bá wọn sunkún. Ẹ ní inú kan sí ara yín. Ẹ má ṣe gbèrò ohun gíga-gíga, ṣugbọn ẹ máa darapọ̀ mọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara yín. Ẹ má máa fi burúkú san burúkú. Ẹ jẹ́ kí èrò ọkàn yín sí gbogbo eniyan máa jẹ́ rere. Ẹ sa ipá yín, níwọ̀n bí ó bá ti ṣeéṣe, láti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu gbogbo eniyan. Ẹ̀yin olùfẹ́, ẹ má máa gbẹ̀san, dípò bẹ́ẹ̀, ẹ máa fún Ọlọrun láàyè láti fi ibinu rẹ̀ hàn. Nítorí Ọlọrun sọ ninu àkọsílẹ̀ pé, “Tèmi ni ẹ̀san, Èmi yóo sì gbẹ̀san.” Ó wà ní àkọsílẹ̀ mìíràn pé, “Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ, bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mu. Nítorí nípa ṣíṣe báyìí, ìwọ yóo wa ẹ̀yinná ìtìjú lé e lórí.” Má jẹ́ kí nǹkan burúkú borí rẹ, ṣugbọn fi ohun rere ṣẹgun nǹkan burúkú. Gbogbo eniyan níláti fi ara wọn sí abẹ́ àwọn aláṣẹ ìlú, nítorí kò sí àṣẹ kan àfi èyí tí Ọlọrun bá lọ́wọ́ sí. Àwọn aláṣẹ tí ó sì wà, Ọlọrun ni ó yàn wọ́n. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fojú di aláṣẹ ń tàpá sí àṣẹ Ọlọrun. Àwọn tí ó bá sì ṣe àfojúdi yóo forí ara wọn gba ìdájọ́. Nítorí àwọn aláṣẹ kò wà láti máa dẹ́rù ba àwọn tí ó ń ṣe rere. Àwọn oníṣẹ́ ibi ni ó ń bẹ̀rù àwọn aláṣẹ. Ṣé o kò fẹ́ kí òfin máa já ọ láyà? Máa ṣe ohun rere, o óo sì gba ìyìn láti ọ̀dọ̀ àwọn aṣòfin. Nítorí iṣẹ́ Oluwa ni àwọn aṣòfin ń ṣe fún rere rẹ. Ṣugbọn bí o bá ń ṣe nǹkan burúkú, o jẹ́ bẹ̀rù! Nítorí kì í ṣe lásán ni idà tí ó wà lọ́wọ́ wọn. Ọlọrun ni ó gbà wọ́n sí iṣẹ́ láti fi ibinu gbẹ̀san lára àwọn tí ó bá ń ṣe nǹkan burúkú. Nítorí náà, eniyan níláti foríbalẹ̀, kì í ṣe nítorí ẹ̀rù ibinu Ọlọrun nìkan, ṣugbọn nítorí pé ẹ̀rí ọkàn wa pàápàá sọ fún wa pé ó yẹ bẹ́ẹ̀. Ìdí kan náà nìyí tí ẹ fi ń san owó-orí. Iṣẹ́ Ọlọrun ni àwọn aláṣẹ ń ṣe, nǹkankan náà tí wọ́n tẹra mọ́ nìyí. Nítorí náà, ẹ san ohun tí ẹ bá jẹ ẹnikẹ́ni pada fún un. Ẹ san owó-orí fún ẹni tí owó-orí tọ́ sí. Ẹ san owó-odè fún ẹni tí owó-odè yẹ. Ẹ bu ọlá fún ẹni tí ọlá bá yẹ. Ẹ má jẹ ẹnikẹ́ni ní gbèsè ohunkohun, àfi gbèsè ìfẹ́ tí ẹ jẹ ara yín. Nítorí ẹni tí ó bá fẹ́ràn ẹnìkejì ti pa gbogbo òfin mọ́. “Fẹ́ràn ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ” ni kókó òfin bíi, “Má ṣe àgbèrè, má jalè, má ṣe ojúkòkòrò,” ati èyíkéyìí tí ó kù ninu òfin. Ìfẹ́ kò jẹ́ ṣe nǹkan burúkú sí ẹnìkejì. Nítorí náà ìfẹ́ ni àkójá òfin. Ó yẹ kí ẹ mọ irú àkókò tí a wà yìí, kí ẹ tají lójú oorun. Nítorí àkókò ìgbàlà wa súnmọ́ tòsí ju ìgbà tí a kọ́kọ́ gbàgbọ́ lọ. Alẹ́ ti lẹ́ tipẹ́. Ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ mọ́. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á pa iṣẹ́ òkùnkùn tì, kí á múra gẹ́gẹ́ bí ọmọ-ogun ìmọ́lẹ̀. Ẹ jẹ́ kí á máa rìn bí ó ti yẹ ní ọ̀sán, kí á má wà ninu àwùjọ aláriwo ati ọ̀mùtí, kí á má máa ṣe ìṣekúṣe, kí á má máa hu ìwà wọ̀bìà, kí á má máa ṣe aáwọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni kí á má máa jowú. Ṣugbọn ẹ gbé Oluwa Jesu Kristi wọ̀ bí ihamọra. Ẹ má jẹ́ kí á máa gbèrò láti ṣe àwọn ohun tí ara fẹ́. Ẹ fa àwọn tí igbagbọ wọn kò tíì fẹsẹ̀ múlẹ̀ mọ́ra, kì í ṣe láti máa bá wọn jiyàn lórí ohun tí kò tó iyàn. Ẹnìkan ní igbagbọ pé kò sí ohun tí òun kò lè jẹ, ṣugbọn ẹni tí igbagbọ rẹ̀ kò tíì fẹsẹ̀ múlẹ̀ rọra ń jẹ ẹ̀fọ́ ní tirẹ̀. Kí ẹni tí ń jẹran má fi ojú tẹmbẹlu ẹni tí kì í jẹ. Kí ẹni tí kì í jẹ má sì ṣe dá ẹni tí ó ń jẹ lẹ́bi, nítorí Ọlọrun ti gbà á. Ta ni ìwọ tí ò ń dá ọmọ-ọ̀dọ̀ ẹlòmíràn lẹ́jọ́? Kì báà dúró, kì báà sì ṣubú, ọ̀gá rẹ̀ nìkan ni ìdájọ́ tọ́ sí. Yóo tilẹ̀ dúró ni, nítorí Oluwa lè gbé e ró. Ẹnìkan ka ọjọ́ kan sí ọjọ́ pataki ju ọjọ́ mìíràn lọ, ẹlòmíràn ka gbogbo ọjọ́ sí bákan náà. Ẹ jẹ́ kí olukuluku pinnu lọ́kàn ara rẹ̀ nípa irú ọ̀ràn báwọ̀nyí. Ẹni tí ó gbé ọjọ́ kan ga ju ọjọ́ mìíràn lọ, ti Oluwa ni ó ń rò. Ẹni tí ó ń jẹ oríṣìíríṣìí oúnjẹ, ó ń jẹ ẹ́ nítorí Oluwa. Ọpẹ́ ni ó ń fi fún Ọlọrun. Ẹni tí kò jẹ, kò jẹ ẹ́ nítorí Oluwa, ọpẹ́ ni òun náà ń fi fún Ọlọrun. Kò sí ẹni tí ó lè wà láàyè fún ara rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni, kò sí ẹni tí ó lè sọ pé, òun nìkan ni ikú òun kàn. Bí a bá wà láàyè, Oluwa ni a wà láàyè fún. Bí a bá sì kú, Oluwa ni a kú fún. Nítorí náà, ààyè wa ni o, òkú wa ni o, ti Oluwa ni wá. Ìdí tí Kristi fi kú nìyí, tí ó sì tún jí, kí ó lè jẹ́ Oluwa àwọn òkú ati ti àwọn alààyè. Kí ni ìdí tí o fi ń dá arakunrin rẹ lẹ́jọ́? Sọ ọ́ kí á gbọ́! Tabi kí ló dé tí ò ń fi ojú tẹmbẹlu arakunrin rẹ? Gbogbo wa mà ni a óo dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Ọlọrun! Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Oluwa fi ara rẹ̀ búra, ó ní, ‘Èmi ni gbogbo orúnkún yóo kúnlẹ̀ fún, Èmi ni gbogbo ẹnu yóo pè ní Ọlọrun.’ ” Nítorí náà, olukuluku wa ni yóo sọ ti ẹnu ara rẹ̀ níwájú Ọlọrun. Ẹ má ṣe jẹ́ kí á máa dá ara wa lẹ́jọ́ mọ́. Ìpinnu kan tí à bá ṣe ni pé, kí á má ṣe fi ohun ìkọsẹ̀ kan, tabi ohunkohun tí yóo ṣi arakunrin wa lọ́nà, sí ojú ọ̀nà rẹ̀. Mo mọ èyí, ó sì dá mi lójú nípa àṣẹ Oluwa Jesu pé kò sí ohunkohun tí ó jẹ́ èèwọ̀ ní jíjẹ fún ara rẹ̀. Ṣugbọn tí ẹnìkan bá ka nǹkan sí èèwọ̀, èèwọ̀ ni fún irú ẹni bẹ́ẹ̀. Nítorí bí o bá mú ìdààmú bá arakunrin rẹ nípa ọ̀ràn oúnjẹ tí ò ń jẹ, a jẹ́ pé, kì í ṣe ìfẹ́ ni ń darí ìgbésí-ayé rẹ mọ́. Má jẹ́ kí oúnjẹ tí ò ń jẹ mú ìparun bá ẹni tí Jesu ti ìtorí rẹ̀ kú. Má ṣe fi ààyè sílẹ̀ fún ìsọkúsọ nípa àwọn ohun tí ẹ kà sí nǹkan rere. Nítorí ìjọba Ọlọrun kì í ṣe ọ̀ràn nǹkan jíjẹ ati nǹkan mímu, ọ̀ràn òdodo, alaafia ati ayọ̀ ninu Ẹ̀mí Mímọ́ ni. Ẹni tí ó bá ń sin Kristi báyìí jẹ́ ẹni tí inú Ọlọrun dùn sí, tí àwọn eniyan sì gbà fún. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á máa lépa àwọn nǹkan tí ń mú alaafia wá, ati àwọn nǹkan tí yóo yọrí sí ìdàgbàsókè láàrin ara wa. Ẹ má ṣe tìtorí oúnjẹ ba iṣẹ́ Ọlọrun jẹ́. A lé sọ pé kò sí oúnjẹ kan tí kò dára, ṣugbọn nǹkan burúkú ni fún ẹni tí ó bá ń jẹ oúnjẹ kan tí ó di nǹkan ìkọsẹ̀ fún ẹlòmíràn. Ó dára bí o kò bá jẹ ẹran, tabi kí o mu ọtí, tabi kí o ṣe ohunkohun tí yóo mú arakunrin rẹ kọsẹ̀. Bí ìwọ bá ní igbagbọ ní tìrẹ, jẹ́ kí igbagbọ tí o ní wà láàrin ìwọ ati Ọlọrun rẹ. Olóríire ni ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò bá dá lẹ́bi lórí nǹkan tí ó bá gbà láti ṣe. Ṣugbọn bí ẹni tí ó ń ṣiyèméjì bá jẹ kinní kan, ó jẹ̀bi, nítorí tí kò jẹ ẹ́ pẹlu igbagbọ. Ẹ̀ṣẹ̀ ni ohunkohun tí eniyan kò bá ṣe pẹlu igbagbọ. Ó yẹ kí àwa tí a jẹ́ alágbára ninu igbagbọ máa fara da àwọn nǹkan tí àwọn tí igbagbọ wọn kò tíì fẹsẹ̀ múlẹ̀ bá ń ṣiyèméjì lé lórí. A kò gbọdọ̀ máa tẹ́ ara wa nìkan lọ́rùn. Olukuluku wa níláti máa ṣe ohun tí yóo tẹ́ ẹnìkejì rẹ̀ lọ́rùn fún ire rẹ̀ ati fún ìdàgbàsókè rẹ̀. Nítorí Kristi kò ṣe nǹkan tí ó tẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn. Dípò bẹ́ẹ̀ ó ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀, “Èmi ni ẹ̀gàn àwọn ẹni tí ó ń gàn ọ́ rẹ́ lára.” Nítorí fún àtikọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ ni a ṣe kọ ohunkohun tí a ti kọ tẹ́lẹ̀, ìdí rẹ̀ ni pé kí ìgboyà ati ìwúrí tí Ìwé Mímọ́ ń fún wa lè fún wa ní ìrètí. Kí Ọlọrun, tí ó ń fún wa ní ìrọ́jú ati ìwúrí, jẹ́ kí ẹ ní ọkàn kan náà sí ara yín gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Kristi Jesu, kí ẹ fi inú kan ati ohùn kan yin Ọlọrun ati Baba Oluwa Jesu Kristi. Nítorí náà, ẹ fa ara yín mọ́ra gẹ́gẹ́ bí Kristi ti gbà yín, kí á lè fi ògo fún Ọlọrun. Ohun tí mò ń sọ ni pé Kristi ti di iranṣẹ fún àwọn tí ó kọlà, láti mú òtítọ́ Ọlọrun ṣẹ, kí ó lè mú àwọn ìlérí tí Ọlọrun ṣe fún àwọn baba-ńlá ṣẹ, ati láti jẹ́ kí àwọn tí kò kọlà lè yin Ọlọrun nítorí àánú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Nítorí èyí, n óo yìn ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, n óo kọrin sí orúkọ rẹ.” Ó tún sọ pé, “Ẹ bá àwọn eniyan rẹ̀ yọ̀, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè.” Ó tún sọ pé, “Ẹ yin Oluwa, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè kí gbogbo eniyan yìn ín.” Aisaya tún sọ pé, “Gbòǹgbò kan yóo ti ìdílé Jese yọ, yóo yọ láti pàṣẹ fún àwọn orílẹ̀-èdè, nítorí lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí àwọn orílẹ̀-èdè wà.” Kí Ọlọrun tí ó ń fúnni ní ìrètí fi ayọ̀ tí ò kún ati alaafia fun yín nípa igbagbọ yín, kí ẹ lè máa dàgbà ninu ìrètí tí ẹ ní ninu Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ̀yin ará, ó dá mi lójú pé ẹ̀yin fúnra yín kún fún inú rere, ẹ ní ìmọ̀ ohun gbogbo, ẹ mọ irú ìmọ̀ràn tí ẹ lè máa gba ara yín. Sibẹ, mo ti fi ìgboyà tẹnumọ́ àwọn kókó ọ̀rọ̀ mélòó kan ninu ìwé yìí, láti ran yín létí nípa wọn. Mo ní ìgboyà láti sọ wọ́n fun yín nítorí oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fún mi láti jẹ́ iranṣẹ Kristi Jesu sí àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Juu. Mò ń ṣe iṣẹ́ alufaa láàrin àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi nípa wiwaasu ìyìn rere Ọlọrun, kí wọ́n lè jẹ́ ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọrun, ọrẹ tí Ẹ̀mí Mímọ́ ti yà sí mímọ́. Nítorí náà, mo ní ohun tí mo lè fi ṣògo ninu Kristi Jesu, ninu iṣẹ́ tí mò ń ṣe fún Ọlọrun. N kò jẹ́ sọ nǹkankan àfi àwọn nǹkan tí Kristi tọwọ́ mi ṣe, láti mú kí àwọn tí wọn kì í ṣe Juu lè gbọ́ràn sí Ọlọrun. Mo ṣe àwọn nǹkan wọnyi nípa ọ̀rọ̀ ati ìṣe mi, pẹlu àwọn àmì ati iṣẹ́ ìyanu tí Ẹ̀mí fún mi lágbára láti ṣe. Àyọrísí èyí ni pé láti Jerusalẹmu títí dé Iliriku ni mo ti waasu ìyìn rere Kristi lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Kì í ṣe àníyàn mi ni láti lọ waasu ìyìn rere níbi tí wọ́n bá ti gbọ́ orúkọ Kristi, kí n má baà kọ́lé lórí ìpìlẹ̀ tí ẹlòmíràn ti fi lélẹ̀. Ṣugbọn àníyàn mi rí bí ọ̀rọ̀ tí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Àwọn ẹni tí kò gbọ́ nípa rẹ̀ rí, yóo rí i. Ọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yóo yé àwọn tí kò gbúròó rẹ̀ rí.” Ìdí nìyí tí mo fi ní ìdènà nígbà pupọ láti wá sọ́dọ̀ yín. Ṣugbọn nisinsinyii, mo ti parí iṣẹ́ mi ní gbogbo agbègbè yìí. Bí mo sì ti ní ìfẹ́ fún ọdún pupọ láti wá sọ́dọ̀ yín, mo lérò láti ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́tẹ̀ yìí. N óo yà sọ́dọ̀ yín nígbà tí mo bá ń kọjá lọ sí Spania. Ìrètí mi ni láti ri yín, kí ẹ lè ràn mí lọ́wọ́, kí n lè débẹ̀, lẹ́yìn tí mo bá ti ní anfaani láti dúró lọ́dọ̀ yín fún ìgbà díẹ̀. Ṣugbọn mò ń lọ sí Jerusalẹmu báyìí láti fi ẹ̀bùn tí wọ́n fi ranṣẹ sí àwọn onigbagbọ tí ó wà níbẹ̀ jíṣẹ́. Nítorí àwọn ìjọ Masedonia ati ti Akaya ti fi inú dídùn ṣe ọrẹ fún àwọn aláìní ninu àwọn onigbagbọ tí ó wà ní Jerusalẹmu. Wọ́n fi inú dídùn ṣe é, ó sì jẹ wọ́n lógún láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí bí àwọn tí kì í ṣe Juu ti pín ninu àwọn nǹkan ti ẹ̀mí ti àwọn onigbagbọ láti Jerusalẹmu, ó yẹ kí wọ́n kà á sí iṣẹ́ ìsìn láti ràn wọ́n lọ́wọ́ pẹlu ohun ìní wọn. Nítorí náà, nígbà tí mo bá parí ètò yìí, tí mo ti fi ọwọ́ ara mi fún wọn ní ohun tí a rí kójọ, n óo gba ọ̀dọ̀ yín kọjá sí Spania. Mo mọ̀ pé, nígbà tí mo bá dé ọ̀dọ̀ yín, n óo wá pẹlu ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ibukun ti Kristi. Ará, mo fi Oluwa wa Jesu Kristi ati ìfẹ́ ti Ẹ̀mí Mímọ́ bẹ̀ yín pé, kí ẹ máa fi ìtara bá mi gbadura sí Ọlọrun pé kí á lè gbà mí lọ́wọ́ àwọn alaigbagbọ ní Judia, ati pé kí iṣẹ́ tí mò ń lọ ṣe ní Jerusalẹmu lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níwájú àwọn onigbagbọ ibẹ̀. Èyí yóo jẹ́ kí n fi ayọ̀ wá sọ́dọ̀ yín, bí Ọlọrun bá fẹ́, tí ọkàn mi yóo fi balẹ̀ nígbà tí mo bá wà lọ́dọ̀ yín. Kí Ọlọrun alaafia kí ó wà pẹlu gbogbo yín. Amin. Mo fẹ́ kí ẹ gba Febe bí arabinrin wa, ẹni tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ ìjọ tí ó wà ní Kẹnkiria. Ẹ gbà á tọwọ́-tẹsẹ̀ ní orúkọ Kristi gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ onigbagbọ. Kí ẹ ràn án lọ́wọ́ ní ọ̀nàkọ́nà tí ó bá fẹ́; nítorí ó jẹ́ ẹni tí ó ran ọpọlọpọ eniyan ati èmi pàápàá lọ́wọ́. Ẹ kí Pirisila ati Akuila, àwọn alábàáṣiṣẹ́ mi ninu iṣẹ́ Kristi Jesu. Wọ́n fi ẹ̀mí wọn wéwu láti gbà mí lọ́wọ́ ikú. Èmi nìkan kọ́ ni mo dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn, gbogbo ìjọ láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu náà dúpẹ́ pẹlu. Ẹ kí ìjọ tí ó wà ní ilé wọn náà. Ẹ kí Epenetu àyànfẹ́ mi, ẹni tí ó jẹ́ onigbagbọ kinni ní ilẹ̀ Esia. Ẹ kí Maria, ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́ pupọ láàrin yín. Ẹ kí Andironiku ati Junia, àwọn ìbátan mi tí a jọ wà lẹ́wọ̀n. Olókìkí ni wọ́n láàrin àwọn òjíṣẹ́ Kristi, wọ́n sì ti di onigbagbọ ṣiwaju mi. Ẹ kí Ampiliatu àyànfẹ́ mi ninu Oluwa. Ẹ kí Ubanu alábàáṣiṣẹ́ mi ninu iṣẹ́ Kristi ati Sitaku àyànfẹ́ mi. Ẹ kí Apele, akikanju onigbagbọ. Ẹ kí àwọn ará ilé Arisitobulu. Ẹ kí Hẹrodioni ìbátan mi. Ẹ kí àwọn ará ilé Nakisu tí wọ́n jẹ́ onigbagbọ. Ẹ kí Tirufina ati Tirufosa, àwọn tí wọn ń ṣe iṣẹ́ Oluwa. Ẹ kí Pasisi, arabinrin àyànfẹ́ tí ó ti ṣiṣẹ́ pupọ ninu Oluwa. Ẹ kí Rufọsi, àṣàyàn onigbagbọ ati ìyá rẹ̀ tí ó tún jẹ́ ìyá tèmi náà. Ẹ kí Asinkiritu, Filegọnta, Herime, Patiroba, Herima ati àwọn arakunrin tí ó wá pẹlu wọn. Ẹ kí Filologu ati Julia, Nerea ati arabinrin rẹ̀, ati Olimpa ati gbogbo àwọn onigbagbọ tí ó wà lọ́dọ̀ wọn. Ẹ rọ̀ mọ́ ara yín, kí ẹ sì kí ara yín pẹlu alaafia. Gbogbo ìjọ Kristi kí yín. Ẹ̀yin ará, mo bẹ̀ yín pé kí ẹ máa fura sí àwọn tí ó ń dá ìyapa sílẹ̀ ati àwọn tí ń múni ṣìnà, tí wọn ń ṣe àwọn nǹkan tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ẹ ti kọ́, ẹ yẹra fún irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀. Nítorí irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀ kì í ṣe iranṣẹ Oluwa wa Kristi, ikùn ara wọn ni wọ́n ń bọ. Wọn a máa fi ọ̀rọ̀ dídùn ati kí á máa pọ́n eniyan tan àwọn tí kò bá fura jẹ. Ìròyìn ti tàn ká ibi gbogbo pé ẹ dúró ṣinṣin ninu igbagbọ. Èyí mú inú mi dùn nítorí yín. Mo fẹ́ kí ẹ jẹ́ amòye ninu nǹkan rere, ṣugbọn kí ẹ jẹ́ òpè ní ti àwọn nǹkan burúkú. Kí Ọlọrun orísun alaafia mu yín ṣẹgun Satani ní kíákíá. Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu kí ó wà pẹlu yín. Timoti alábàáṣiṣẹ́ mi ki yín. Bẹ́ẹ̀ náà ni Lukiusi ati Jasoni ati Sosipata, àwọn ìbátan wa. Èmi Tatiu tí mò ń bá Paulu kọ ìwé yìí ki yín: Ẹ kú iṣẹ́ Oluwa. Gaiyu náà ki yín. Òun ni ó gbà mí lálejò bí ó ti gba gbogbo ìjọ lálejò. Erastu, akápò ìlú, ki yín. Kuatu arakunrin wa náà ki yín. [ Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu Kristi kí ó wà pẹlu gbogbo yín. Amin.] Ògo ni fún ẹni tí ó lágbára láti mu yín dúró gbọningbọnin, gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere ati iwaasu nípa Jesu Kristi ti wí ati gẹ́gẹ́ bí àdììtú tí Ọlọrun dì láti ayérayé, ṣugbọn tí ó wá tú ní àkókò yìí. Ìwé àwọn wolii ni ó ṣe ìṣípayá ohun tí ó fara pamọ́ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Ọlọrun ayérayé, pé kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè gbọ́, kí wọ́n mọ̀, kí wọ́n sì gbà. Ògo ni fún Ọlọrun ọlọ́gbọ́n kanṣoṣo nípa Jesu Kristi títí laelae. Amin. Èmi Paulu, tí Ọlọrun pè láti jẹ́ òjíṣẹ́ Kristi Jesu, ati Sositene arakunrin wa ni à ń kọ ìwé yìí— Sí ìjọ Ọlọrun ti ó wà ní Kọrinti, àwọn tí a yà sí mímọ́ nípa ìṣọ̀kan pẹlu Kristi Jesu, tí a pè láti jẹ́ eniyan ọ̀tọ̀, ati gbogbo àwọn tí ń pe orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi níbi gbogbo, Jesu tíí ṣe Oluwa tiwọn ati tiwa. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba wa ati Oluwa Jesu Kristi kí ó máa wà pẹlu yín. Mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun mi nígbà gbogbo nítorí yín, nítorí oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fun yín ninu Kristi Jesu. Nítorí pé ẹ ní ọpọlọpọ ẹ̀bùn ninu Kristi: ẹ ní ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ, ẹ sì tún ní ẹ̀bùn ìmọ̀. Ẹ̀rí Kristi ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ láàrin yín, tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé kò sí ẹ̀bùn Ẹ̀mí kan tí ó kù tí ẹ kò ní. Ẹ wá ń fi ìtara retí ìfarahàn Oluwa wa Jesu Kristi, ẹni tí yóo fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀ títí dé òpin, tí ẹ óo fi wà láì lẹ́gàn ní ọjọ́ ìfarahàn Oluwa wa, Jesu Kristi. Ẹni tí ó tó gbẹ́kẹ̀lé ni Ọlọrun tí ó pè yín sinu ìṣọ̀kan pẹlu ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi, Oluwa wa. Ẹ̀yin ará, mo fi orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi bẹ̀ yín, gbogbo yín, ẹ fohùn ṣọ̀kan, kí ó má sí ìyapa láàrin yín. Ẹ jẹ́ kí ọkàn yín ṣe ọ̀kan, kí èrò yín sì papọ̀. Nítorí pé ninu ìròyìn tí àwọn ará Kiloe mú wá, ó hàn sí mi gbangba pé ìjà wà láàrin yín. Ohun tí mò ń wí ni pé olukuluku yín ní ń sọ tirẹ̀. Bí ẹnìkan ti ń wí pé. “Ẹ̀yìn Paulu ni èmi wà,” ni ẹlòmíràn ń wí pé. “Ẹ̀yìn Apolo ni èmi wà,” tí ẹlòmíràn tún ń wí pé, “Ẹ̀yìn Peteru ni mo wà ní tèmi.” Ẹlòmíràn sì ń wí pé, “Ẹ̀yìn Kristi ni èmi wà.” Ṣé Kristi náà ni ó wá pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ báyìí? Ṣé èmi Paulu ni wọ́n kàn mọ́ agbelebu fun yín? Àbí ní orúkọ Paulu ni wọ́n ṣe ìrìbọmi fun yín? Mo dúpẹ́ pé n kò ṣe ìrìbọmi fún ẹnikẹ́ni ninu yín, àfi Kirisipu ati Gaiyu. Kí ẹnikẹ́ni má baà wí pé orúkọ mi ni wọ́n fi ṣe ìrìbọmi fún òun. Mo tún ranti! Mo ṣe ìrìbọmi fún ìdílé Stefana. N kò tún ranti ẹlòmíràn tí mo ṣe ìrìbọmi fún mọ́. Nítorí pé Kristi kò fi iṣẹ́ ṣíṣe ìrìbọmi rán mi, iṣẹ́ iwaasu ìyìn rere ni ó fi rán mi, kì í sìí ṣe nípa ọ̀rọ̀ ọgbọ́n, kí agbelebu Kristi má baà di òfo. Nítorí ọ̀rọ̀ agbelebu Kristi jẹ́ ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ lójú àwọn tí ń ṣègbé. Ṣugbọn lójú àwọn tí à ń gbà là, agbára Ọlọrun ni. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ọlọrun wí pé, ‘Èmi óo pa ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n run, n óo pa ìmọ̀ àwọn amòye tì sápá kan.’ ” Ipò wo wá ni àwọn ọlọ́gbọ́n wà? Àwọn amòfin ńkọ́? Àwọn tí wọ́n mọ iyàn jà ní ayé yìí ńkọ́? Ṣebí Ọlọrun ti sọ ọgbọ́n ayé yìí di agọ̀! Bí ó ti jẹ́ ìfẹ́ Ọlọrun pé kì í ṣe ipasẹ̀ gbogbo ọgbọ́n ayé yìí ni eniyan yóo fi mọ Ọlọrun, ó wu Ọlọrun láti gba àwọn tí ó gbàgbọ́ là nípa iwaasu tí à ń wà, tí ó dàbí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀. Nítorí àwọn Juu ń bèèrè àmì: àwọn Giriki ń lépa ọgbọ́n; ṣugbọn ní tiwa, àwa ń waasu Kristi tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu. Ohun ìkọsẹ̀ ni iwaasu wa yìí jẹ́ lójú àwọn Juu, ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ sì ni lójú àwọn orílẹ̀-èdè yòókù; ṣugbọn lójú àwọn tí Ọlọrun pè, ìbáà ṣe Juu tabi Giriki, Kristi yìí ni agbára Ọlọrun, òun ni ọgbọ́n Ọlọrun. Nítorí agọ̀ Ọlọrun gbọ́n ju eniyan lọ, àìlágbára Ọlọrun sì lágbára ju eniyan lọ! Ẹ̀yin ará, ẹ wo ọ̀nà tí Ọlọrun gbà pè yín. Kì í ṣe ọ̀pọ̀ ninu yín ni ọlọ́gbọ́n gẹ́gẹ́ bí èrò ẹ̀dá, ọ̀pọ̀ ninu yín kì í ṣe alágbára, ọ̀pọ̀ ninu yín kì í ṣe ọlọ́lá. Ṣugbọn Ọlọrun ti yan àwọn nǹkan tí ayé kà sí agọ̀ láti fi dójú ti àwọn ọlọ́gbọ́n, ó yan àwọn nǹkan tí kò lágbára ti ayé, láti fi dójú ti àwọn alágbára; bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun yan àwọn ẹni tí kò níláárí ati àwọn ẹni tí kò já mọ́ nǹkankan rárá, àwọn tí ẹnikẹ́ni kò kà sí, láti rẹ àwọn tí ayé ń gbé gẹ̀gẹ̀ sílẹ̀. Ìdí tí Ọlọrun fi ṣe báyìí ni pé kí ẹnikẹ́ni má baà lè gbéraga níwájú òun. Nípa iṣẹ́ Ọlọrun, ẹ̀yin wà ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi Jesu. Òun ni Ọlọrun fi ṣe ọgbọ́n wa ati òdodo wa. Òun ni ó sọ wá di mímọ́, tí ó dá wa nídè. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pe: “Ẹni tí ó bá fẹ́ ṣe ìgbéraga, kí ó ṣe ìgbéraga nípa ohun tí Oluwa ṣe.” Ẹ̀yin ará, nígbà tí mo dé ọ̀dọ̀ yín, n kò wá fi ọ̀rọ̀ dídùn tabi ọgbọ́n eniyan kéde àṣírí Ọlọrun fun yín. Nítorí mo ti pinnu pé n kò fẹ́ mọ ohunkohun láàrin yín yàtọ̀ fún Jesu Kristi: àní, ẹni tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu. Pẹlu àìlera ati ọpọlọpọ ìbẹ̀rù ati ìkọminú ni mo fi wá sọ́dọ̀ yín. Ọ̀rọ̀ mi ati iwaasu mi kì í ṣe láti fi ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tí ó dùn létí yi yín lọ́kàn pada, iṣẹ́ Ẹ̀mí ati agbára Ọlọrun ni mo fẹ́ fihàn; kí igbagbọ yín má baà dúró lórí ọgbọ́n eniyan bíkòṣe lórí agbára Ọlọrun. À ń sọ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n fún àwọn tí igbagbọ wọn ti fẹsẹ̀ múlẹ̀, ṣugbọn kì í ṣe ọgbọ́n ti ayé yìí, kì í sìí ṣe ti àwọn aláṣẹ ayé yìí, agbára tiwọn ti fẹ́rẹ̀ pin. Ṣugbọn à ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n Ọlọrun, ohun àṣírí tí ó ti wà ní ìpamọ́, tí Ọlọrun ti ṣe ètò sílẹ̀ láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé fún ògo wa. Kò sí ọ̀kan ninu àwọn aláṣẹ ayé yìí tí ó mọ àṣírí yìí, nítorí tí ó bá jẹ́ pé wọ́n mọ̀ ọ́n ni, wọn kì bá tí kan Oluwa tí ó lógo mọ́ agbelebu. Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ohun tí ojú kò ì tíì rí, tí etí kò ì tíì gbọ́, Ohun tí kò wá sí ọkàn ẹ̀dá kan rí, ni ohun tí Ọlọrun ti pèsè sílẹ̀ fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀.” Nǹkan yìí ni Ọlọrun fi àṣírí rẹ̀ hàn wá nípa Ẹ̀mí. Ẹ̀mí ní ń wádìí ohun gbogbo títí fi kan àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọrun. Nítorí ẹ̀dá alààyè wo ni ó mọ ohun tí ó wà ninu eniyan kan bíkòṣe ẹ̀mí olúwarẹ̀ tí ó wà ninu rẹ̀? Bẹ́ẹ̀ gan-an ni àwọn nǹkan Ọlọrun: kò sí ẹni tí ó mọ̀ wọ́n àfi Ẹ̀mí Ọlọrun. Ṣugbọn ní tiwa, kì í ṣe ẹ̀mí ti ayé ni a gbà. Ẹ̀mí láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni ó fi fún wa, kí á lè mọ àwọn ẹ̀bùn tí Ọlọrun ti fún wa. Ohun tí à ń sọ kì í ṣe ohun tí eniyan fi ọ̀rọ̀ ọgbọ́n kọ́ wa. Ẹ̀mí ni ó kọ́ wa bí a ti ń túmọ̀ nǹkan ti ẹ̀mí, fún àwọn tí wọ́n ní Ẹ̀mí. Ṣugbọn eniyan ẹlẹ́ran-ara kò lè gba àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí Ọlọrun, nítorí bí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ ni yóo rí lójú rẹ̀. Kò tilẹ̀ lè yé e, nítorí pé ẹni tí ó bá ní Ẹ̀mí ni ó lè yé. Ẹni tí ó bá ní Ẹ̀mí lè wádìí ohun gbogbo, ṣugbọn eniyan kan lásán kò lè wádìí òun alára. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ta ni ó mọ inú Oluwa? Ta ni yóo kọ́ Oluwa lẹ́kọ̀ọ́?” Ṣugbọn irú ẹ̀mí tí Kristi ní ni àwa náà ní. Ẹ̀yin ará, n kò lè ba yín sọ̀rọ̀ bí ẹni ti Ẹ̀mí, bíkòṣe bí ẹlẹ́ran-ara, àní gẹ́gẹ́ bí ọmọ-ọwọ́ ninu Kristi. Wàrà ni mo ti fi ń bọ yín, kì í ṣe oúnjẹ gidi, nítorí nígbà náà ẹ kò ì tíì lè jẹ oúnjẹ gidi. Àní títí di ìsinsìnyìí ẹ kò ì tíì lè jẹ ẹ́, nítorí bí ẹlẹ́ran-ara ni ẹ̀ ń hùwà sibẹ. Nítorí níwọ̀n ìgbà tí owú jíjẹ ati ìjà bá wà láàrin yín, ṣé kò wá fihàn pé bí ẹlẹ́ran-ara ati eniyan kan lásán ni ẹ̀ ń hùwà. Nítorí nígbà tí ẹnìkan ń sọ pé ẹ̀yìn Paulu ni òun wà, tí ẹlòmíràn ń sọ pé ẹ̀yìn Apolo ni òun wà ní tòun, ó fihàn pé bí eniyan kan lásán ni ẹ̀ ń hùwà. Nítorí ta ni Apolo? Ta ni Paulu? Ṣebí iranṣẹ ni wọ́n, tí ẹ ti ipasẹ̀ wọn di onigbagbọ? Olukuluku wọn jẹ́ iṣẹ́ tirẹ̀ bí Ọlọrun ti rán an. Èmi gbin irúgbìn, Apolo bomi rin ohun tí mo gbìn, ṣugbọn Ọlọrun ni ó ń mú kí ohun ọ̀gbìn dàgbà. Nítorí èyí, kì í ṣe ẹni tí ń gbin nǹkan, tabi ẹni tí ń bomi rin ín ni ó ṣe pataki, bíkòṣe Ọlọrun tí ó ń mú un dàgbà. Ọ̀kan ni ẹni tí ó ń gbin irúgbìn ati ẹni tí ó ń bomi rin ín. Nígbà tí ó bá yá, ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn yóo gba èrè tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ bá ti rí. Nítorí alábàáṣiṣẹ́pọ̀ ni wá lọ́dọ̀ Ọlọrun. Ẹ̀yin ni ọgbà Ọlọrun. Tẹmpili Ọlọrun sì ni yín. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀lé tí ó mòye, mo fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ nípa oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fi fún mi, ẹlòmíràn wá ń kọ́lé lé e lórí. Ṣugbọn kí olukuluku ṣọ́ra pẹlu irú ohun tí ó ń mọ lé orí ìpìlẹ̀ yìí. Nítorí kò sí ìpìlẹ̀ kan tí ẹnikẹ́ni tún lè fi lélẹ̀ mọ́, yàtọ̀ sí èyí tí Ọlọrun ti fi lélẹ̀, tíí ṣe Jesu Kristi. Ṣugbọn bí ẹnikẹ́ni bá mọ wúrà, tabi fadaka, tabi òkúta iyebíye, tabi igi, tabi koríko tabi fùlùfúlù lé orí ìpìlẹ̀ yìí, iṣẹ́ olukuluku yóo farahàn kedere ní ọjọ́ ìdájọ́, nítorí iná ni yóo fi í hàn. Iná ni a óo fi dán iṣẹ́ olukuluku wò. Bí ohun tí ẹnikẹ́ni bá kọ́ lé orí ìpìlẹ̀ yìí kò bá jóná, olúwarẹ̀ yóo gba èrè. Bí iṣẹ́ ẹnikẹ́ni bá jóná, olúwarẹ̀ yóo pòfo, ṣugbọn òun alára yóo lá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé bí ẹni tí a fà yọ ninu iná ni. Àbí ẹ kó mọ̀ pé Tẹmpili Ọlọrun ni yín ni, ati pé Ẹ̀mí Ọlọrun ń gbé inú yín? Bí ẹnikẹ́ni bá ba Tẹmpili Ọlọrun jẹ́. Ọlọrun yóo pa òun náà run. Nítorí mímọ́ ni Tẹmpili Ọlọrun, ẹ̀yin náà sì ni Tẹmpili Ọlọrun. Kí ẹnikẹ́ni má ṣe tan ara rẹ̀ jẹ. Bí ẹnìkan ninu yín bá rò pé òun gbọ́n ọgbọ́n ti ayé yìí, kí ó ka ara rẹ̀ sí òmùgọ̀ kí ó lè gbọ́n. Nítorí agọ̀ ni ọgbọ́n ayé yìí lójú Ọlọrun. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ẹni tí ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n ninu àrékérekè wọn.” Níbòmíràn, ó tún wí pé, “Oluwa mọ̀ pé asán ni èrò-inú àwọn ọlọ́gbọ́n.” Nítorí náà, kí ẹnikẹ́ni má ṣe tìtorí eniyan gbéraga, nítorí tiyín ni ohun gbogbo: ati Paulu ni, ati Apolo, ati Peteru, ati ayé yìí, ati ìyè, ati ikú, ati àwọn nǹkan ìsinsìnyìí ati àwọn nǹkan àkókò tí ń bọ̀, tiyín ni ohun gbogbo. Ṣugbọn ti Kristi ni yín, Kristi sì jẹ́ ti Ọlọrun. Bí ó ti yẹ kí eniyan máa rò nípa wa ni pé a jẹ́ iranṣẹ Kristi ati ìríjú àwọn nǹkan àṣírí Ọlọrun. Ohun tí à ń retí lọ́dọ̀ ìríjú ni pé kí ó jẹ́ olóòótọ́. Kò ṣe mí ní nǹkankan bí ẹ bá ń dá mi lẹ́jọ́ tabi bí ẹnikẹ́ni bá ń dá mi lẹ́jọ́. Èmi fúnra mi kì í tilẹ̀ dá ara mi lẹ́jọ́. Ọkàn mi mọ́, ṣugbọn n kò wí pé mo pé, Oluwa ni ẹni tí ó ń ṣe ìdájọ́ mi. Nítorí náà, kí ẹnikẹ́ni má ṣe ìdájọ́ kí àkókò rẹ̀ tó tó, nígbà tí Oluwa yóo dé, tí yóo tan ìmọ́lẹ̀ sí ohun gbogbo tí ó fara pamọ́ sinu òkùnkùn, tí yóo mú kí gbogbo èrò ọkàn eniyan farahàn kedere. Nígbà náà ni olukuluku yóo gba iyìn tí ó yẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Ẹ̀yin ará, mo fi ara mi ati Apolo ṣe àpẹẹrẹ ohun tí à ń sọ nítorí yín, kí ẹ lè kọ́ ẹ̀kọ́ lára wa, pé kí ẹ má ṣe tayọ ohun tí ó wà ní àkọsílẹ̀. Ẹ kò gbọdọ̀ gbé ẹnìkan ga ju ẹnìkejì lọ. Ta ni ó gbe yín ga ju ẹlòmíràn lọ? Kí ni ohun tí ẹ dá ní, tí kò jẹ́ pé ọwọ́ Ọlọrun ni ẹ ti rí i gbà? Kí wá ni ìdí ìgbéraga yín bí ẹni pé ẹ̀yin ni ẹ dá a ní? Ṣé gbogbo nǹkan ti tẹ yín lọ́rùn! Ẹ ti di ọlọ́rọ̀! Ẹ gbàgbé wa sẹ́yìn, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí jọba! Kì bá wù mí kí ẹ jọba nítòótọ́ kí àwa náà lè ba yín jọba! Nítorí mo rò pé Ọlọrun ti fi àwa òjíṣẹ́ hàn ní ìkẹyìn bí àwọn tí a dá lẹ́bi ikú, nítorí a ti di ẹni tí gbogbo ayé fi ń ṣe ìran wò: ati àwọn angẹli, ati àwọn eniyan. Àwa di òmùgọ̀ nítorí ti Kristi, ẹ̀yin wá jẹ́ ọlọ́gbọ́n ninu Kristi! Àwa jẹ́ aláìlera, ẹ̀yin jẹ́ alágbára! Ẹ̀yin jẹ́ ọlọ́lá, àwa jẹ́ aláìlọ́lá! Títí di bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí, ebi ń pa wá, òùngbẹ ń gbẹ wá, aṣọ sì di àkísà mọ́ wa lára. Wọ́n ń lù wá, a kò sì ní ibùgbé kan tààrà. Àárẹ̀ mú wa bí a ti ń fi ọwọ́ ara wa ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa. Àwọn eniyan ń bú wa, ṣugbọn àwa ń súre fún wọn. Wọ́n ń ṣe inúnibíni wa, ṣugbọn à ń fara dà á. Wọ́n ń sọ̀rọ̀ burúkú sí wa, ṣugbọn àwa ń sọ̀rọ̀ ìwúrí. A di ohun ẹ̀sín fún gbogbo ayé. A di pàǹtí fún gbogbo eniyan títí di bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí. Kì í ṣe pé mo fẹ́ dójú tì yín ni mo fi ń kọ nǹkan wọnyi si yín, mò ń kìlọ̀ fun yín gẹ́gẹ́ bí àyànfẹ́ ọmọ mi ni. Nítorí pé, ẹ̀ báà ní ẹgbẹrun àwọn olùtọ́ ninu Kristi, ẹ kò ní ju ẹyọ baba kan lọ. Nítorí ninu Kristi Jesu, èmi ni mo bi yín nípa ọ̀rọ̀ ìyìn rere. Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ fi ìwà jọ mí. Ìdí tí mo ṣe rán Timoti si yín nìyí, ẹni tí ó jẹ́ àyànfẹ́ ọmọ fún mi, ati olóòótọ́ ninu nǹkan ti Oluwa. Òun ni yóo ran yín létí àwọn ohun tí mo fi ń ṣe ìwà hù ninu ìgbé-ayé titun ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi Jesu, gẹ́gẹ́ bí mo ti ń kọ́ gbogbo àwọn ìjọ níbi gbogbo. Àwọn kan ti ń gbéraga bí ẹni pé n kò ní wá sọ́dọ̀ yín. Ṣugbọn mò ń bọ̀ láìpẹ́, bí Oluwa bá fẹ́. N óo wá mọ agbára tí àwọn tí wọn ń gbéraga ní nígbà náà, yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn lásán. Nítorí ìjọba Ọlọrun kì í ṣe ti ọ̀rọ̀ ẹnu: ti agbára ni! Kí ni ẹ fẹ́? Kí n tọ̀ yín wá pẹlu pàṣán ni, tabi pẹlu ẹ̀mí ìfẹ́ ati ní ìrẹ̀lẹ̀? A gbọ́ dájúdájú pé ìwà àgbèrè wà láàrin yín, irú èyí tí kò tilẹ̀ sí láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu. A gbọ́ pé ẹnìkan ń bá iyawo baba rẹ̀ lòpọ̀! Dípò èyí tí ọkàn yín ìbá fi bàjẹ́, tí ẹ̀ bá sì yọ ẹni tí ń ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kúrò láàrin yín, ẹ wá ń ṣe fáàrí! Bí èmi alára kò tilẹ̀ sí lọ́dọ̀ yín mo wà lọ́dọ̀ yín ninu ẹ̀mí. Mo ti ṣe ìdájọ́ ẹni tí ó ṣe nǹkan bẹ́ẹ̀ ní orúkọ Jesu Oluwa bí ẹni pé mo wà lọ́dọ̀ yín. Nígbà tí ẹ bá péjọ pọ̀, tí ẹ̀mí mi sì wà pẹlu yín, pẹlu agbára Oluwa wa Jesu, *** ẹ fi irú ẹni bẹ́ẹ̀ fún Satani, kí Satani lè pa ara rẹ̀ run, kí á lè gba ẹ̀mí rẹ̀ là ní ọjọ́ ìfarahàn Oluwa wa. Fáàrí tí ẹ̀ ń ṣe kò dára! Ẹ kò mọ̀ pé ìwúkàrà díẹ̀ ni ó ń mú burẹdi wú sókè? Ẹ mú ìwúkàrà àtijọ́ kúrò, kí ẹ lè dàbí burẹdi titun, ẹ óo wá di burẹdi titun ti kò ní ìwúkàrà ninu. Nítorí a ti fi Kristi ọ̀dọ́ aguntan Ìrékọjá wa rúbọ. Nítorí náà ẹ jẹ́ kí á ṣe Àjọ̀dún Ìrékọjá wa, kì í ṣe burẹdi tí ó ní ìwúkàrà àtijọ́ ti ẹ̀ṣẹ̀ ati ìwà burúkú ni kí á fi ṣe é, ṣugbọn pẹlu burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, burẹdi ìwà mímọ́ ati òtítọ́. Mo kọ ìwé si yín pé kí ẹ má ṣe darapọ̀ mọ́ àwọn tí ń hùwà ìbàjẹ́. Kì í ṣe pé kí ẹ yẹra patapata fún àwọn alaigbagbọ tí ń hùwà àgbèrè, tabi tí ó ní ojúkòkòrò, tabi oníjìbìtì, tabi abọ̀rìṣà. Nítorí ẹ óo níláti jáde kúrò ninu ayé tí ẹ kò bá bá irú àwọn wọnyi lò. Ohun tí mo kọ si yín ni pé kí ẹ má ṣe darapọ̀ mọ́ ẹnikẹ́ni tí a bá ń pè ní onigbagbọ tí ó ń hùwà àgbèrè, tabi ti ó ní ojúkòkòrò, tabi tí ó jẹ́ abọ̀rìṣà, tabi abanijẹ́, tabi ọ̀mùtí, tabi oníjìbìtì. Ẹ má tilẹ̀ bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹun. Èwo ni tèmi láti dá alaigbagbọ lẹ́jọ́? Ṣebí àwọn onigbagbọ ara yín ni ẹ̀ ń dá lẹ́jọ́? Ọlọrun ni ó ń ṣe ìdájọ́ àwọn alaigbagbọ. Ẹ yọ ẹni burúkú náà kúrò láàrin yín. Kí ló dé tí ẹni tí ó bá ní ẹ̀sùn sí ẹnìkejì rẹ̀ fi ń gbé ẹjọ́ lọ siwaju àwọn alaigbagbọ? Àbí ẹ kò mọ̀ pé àwọn onigbagbọ ni yóo ṣe ìdájọ́ ayé? Nígbà tí ó jẹ́ pé ẹ̀yin ni ẹ óo ṣe ìdájọ́ ayé, ó ti wá jẹ́ tí ẹ kò fi lè ṣe ìdájọ́ àwọn tí ó kéré jùlọ? Àbí ẹ kò mọ̀ pé àwa onigbagbọ ni yóo ṣe ìdájọ́ àwọn angẹli! Mélòó-mélòó wá ni àwọn nǹkan ti ayé yìí? Bí ẹ bá ní ẹ̀sùn nípa nǹkan ti ayé, kí ló dé ti ẹ fi ń pe àwọn alaigbagbọ tí kò lẹ́nu ninu ìjọ láti máa jókòó lórí ọ̀rọ̀ yín? Kí ojú baà lè tì yín ni mo fi ń sọ̀rọ̀ báyìí! Ṣé kò wá sí ẹnikẹ́ni láàrin yín tí ó gbọ́n tó láti dá ẹjọ́ fún ẹnìkan ati arakunrin rẹ̀ ni? Dípò kí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀, onigbagbọ ń pe onigbagbọ lẹ́jọ́ níwájú àwọn alaigbagbọ! Nǹkankan kù díẹ̀ kí ó tó nípa igbagbọ yín. Òun ni ó mú kí ẹ máa ní ẹ̀sùn sí ara yín. Kí ni kò jẹ́ kí olukuluku yín kúkú máa gba ìwọ̀sí? Kí ni kò jẹ́ kí ẹ máa gba ìrẹ́jẹ? Kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ni ẹ̀ ń fi ìwọ̀sí kan ara yín tí ẹ̀ ń rẹ́ ara yín jẹ, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ onigbagbọ! Àbí ẹ kò mọ̀ pé kò sí alaiṣododo kan tí yóo jogún ìjọba Ọlọrun? Ẹ má tan ara yín jẹ, kò sí àwọn oníṣekúṣe, tabi àwọn abọ̀rìṣà, àwọn àgbèrè tabi àwọn oníbàjẹ́, tabi àwọn tí ó ń bá ọkunrin lòpọ̀ bí obinrin; àwọn olè tabi àwọn olójúkòkòrò, àwọn ọ̀mùtí-para tabi àwọn abanijẹ́, tabi àwọn oníjìbìtì, tí yóo jogún ìjọba Ọlọrun. Àwọn mìíràn wà ninu yín tí wọn ń hu irú ìwà báyìí tẹ́lẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, a ti wẹ̀ yín mọ́, a ti yà yín sọ́tọ̀, a ti da yín láre nípa orúkọ Oluwa Jesu Kristi ati nípa Ẹ̀mí Ọlọrun wa. Ẹnìkan lè sọ pé, “Kò sí ohun tí kò tọ̀nà fún mi láti ṣe.” Bẹ́ẹ̀ ni, ṣugbọn kì í ṣe gbogbo nǹkan tí o lè ṣe ni yóo ṣe ọ́ ní anfaani. Kò sí ohun tí kò tọ̀nà fún mi láti ṣe, ṣugbọn n kò ní jẹ́ kí ohunkohun jọba lé mi lórí. Oúnjẹ wà fún ikùn, ikùn sì wà fún oúnjẹ. Ṣugbọn ati oúnjẹ ati ikùn ni Ọlọrun yóo parun. Ara kò wà fún ṣíṣe àgbèrè bíkòṣe pé kí á lò ó fún Oluwa. Bẹ́ẹ̀ ni Oluwa wà fún ara. Bí Ọlọrun ti jí Oluwa dìde kúrò ninu òkú, bẹ́ẹ̀ ní yóo jí àwa náà pẹlu agbára rẹ̀. Àbí ẹ kò mọ̀ pé ẹ̀yà ara Kristi ni àwọn ẹ̀yà ara yín jẹ́? Ṣé kí a wá sọ ẹ̀yà ara Kristi di ẹ̀yà ara àgbèrè ni? Ọlọrun má jẹ̀ẹ́! Àbí ẹ kò mọ̀ pé ẹni tí ó bá alágbèrè lòpọ̀ ti di ara kan pẹlu rẹ̀? Ìwé Mímọ́ sọ pé. “Àwọn mejeeji yóo di ara kan.” Ṣugbọn ẹni tí ó bá ní ìdàpọ̀ pẹlu Oluwa di ọ̀kan pẹlu rẹ̀ ninu ẹ̀mí. Ẹ sá fún ìwà àgbèrè. Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí eniyan lè máa dá kò kan ara olúwarẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí ó ń ṣe àgbèrè ń ṣẹ̀ sí ara òun tìkararẹ̀. Àbí, ẹ kò mọ̀ pé ara yín ni ibùgbé Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó wà ninu yín, tí ẹ gbà láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun? Ati pé kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ ni ara yín? Iyebíye ni Ọlọrun rà yín, nítorí náà, ẹ fi ara yín yin Ọlọrun. Ọ̀rọ̀ lórí àwọn nǹkan tí ẹ kọ nípa rẹ̀, ó dára tí ọkunrin bá lè ṣe é kí ó má ní obinrin rara. Ṣugbọn nítorí àgbèrè, kí olukuluku ọkunrin ní aya tirẹ̀; kí olukuluku obinrin sì ní ọkọ tirẹ̀. Ọkọ gbọdọ̀ máa ṣe ẹ̀tọ́ pẹlu iyawo rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni iyawo náà gbọdọ̀ máa ṣe ẹ̀tọ́ pẹlu ọkọ rẹ̀. Kì í ṣe iyawo ni ó ni ara rẹ̀, ọkọ rẹ̀ ni ó ni í; bákan náà ni ọkọ, òun náà kò dá ara rẹ̀ ni, iyawo rẹ̀ ni ó ni í. Ọkọ ati aya kò gbọdọ̀ fi ara wọn du ara wọn, àfi bí wọ́n bá jọ gbà pé fún àkókò díẹ̀ àwọn yóo yàgò fún ara àwọn, kí wọ́n lè tẹra mọ́ adura gbígbà. Lẹ́yìn àkókò díẹ̀ yìí, kí wọn tún máa bá ara wọn lòpọ̀, kí Satani má baà dán wọn wò, tí wọn kò bá lè mú ara dúró. Mo sọ èyí kí ẹ lè mọ̀ pé mo yọ̀ǹda fun yín pé kí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ ni; kì í ṣe pé mo pa á láṣẹ. Ohun tí ìbá wù mí fun yín ni pé kí gbogbo eniyan rí bí mo ti rí; ṣugbọn ẹ̀bùn tí Ọlọrun fún olukuluku yàtọ̀, ó fún àwọn kan ní oríṣìí kan, ó fún àwọn mìíràn ní oríṣìí mìíràn. Mò ń sọ fún àwọn tí kò ì tíì gbeyawo ati fún àwọn opó pé ó dára fún wọn láti dá wà, bí mo ti wà. Ṣugbọn bí wọn kò bá lè mú ara dúró, wọ́n níláti gbeyawo. Nítorí ó sàn kí wọ́n gbeyawo jù pé kí ara wọn máa gbóná nítorí èrò ìbálòpọ̀ ọkunrin ati obinrin. Mo ní ọ̀rọ̀ fún àwọn tí ó ti gbeyawo: ọ̀rọ̀ tèmi fúnra mi kọ́, bíkòṣe ti Oluwa wa. Aya kò gbọdọ̀ kọ ọkọ rẹ̀. Bí ó bá kọ ọkọ rẹ̀, ó níláti dá wà ni, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ó bá ọkọ rẹ̀ rẹ́, kí ó pada sọ́dọ̀ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ọkọ náà kò gbọdọ̀ kọ aya rẹ̀. Mo ní ọ̀rọ̀ fún ẹ̀yin yòókù, (èrò tèmi ni o, kì í ṣe ọ̀rọ̀ Oluwa wa.) Bí ọkunrin onigbagbọ kan bá ní aya tí kì í ṣe onigbagbọ, tí ó bá wu aya rẹ̀ láti máa bá a gbé, kí ọkọ má ṣe kọ̀ ọ́. Bí obinrin onigbagbọ bá ní ọkọ tí kì í ṣe onigbagbọ, tí ó bá wu ọkọ rẹ̀ láti máa bá a gbé, kí ó má ṣe kọ ọkọ rẹ̀. Nítorí ọkọ tí kì í ṣe onigbagbọ di ẹni Ọlọrun nípa aya rẹ̀, aya tí kì í ṣe onigbagbọ di ẹni Ọlọrun nípa ọkọ rẹ̀. Bí èyí kò bá rí bẹ́ẹ̀, alaimỌlọrun ni àwọn ọmọ yín ìbá jẹ́ ṣugbọn nisinsinyii ẹni Ọlọrun ni wọ́n. Ṣugbọn bí ẹni tí kì í ṣe onigbagbọ bá yàn láti fi ẹnìkejì tí ó jẹ́ onigbagbọ sílẹ̀, kí ó fi í sílẹ̀. Kò sí ọ̀ranyàn fún ọkọ tabi aya tí ó jẹ́ onigbagbọ ninu irú ọ̀ràn báyìí. Kí ẹ jọ wà ní alaafia ní ipò tí Ọlọrun pè yín sí. Nítorí, ta ni ó mọ̀, bóyá ìwọ aya ni yóo gba ọkọ rẹ là? Tabi ta ni ó mọ̀, ìwọ ọkọ, bóyá ìwọ ni o óo gba aya rẹ là? Kí olukuluku máa gbé ìgbé-ayé rẹ̀ bí Oluwa ti yàn án fún un, kí ó sì wà ní ipò tí ó wà nígbà tí Ọlọrun fi pè é láti di onigbagbọ. Bẹ́ẹ̀ ni mò ń fi kọ́ gbogbo àwọn ìjọ. Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ ẹni tí ó kọlà nígbà tí a pè é, kí ó má ṣe pa ilà rẹ̀ rẹ́. Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ aláìkọlà nígbà tí a pè é, kí ó má ṣe kọlà. Ati a kọlà ni, ati a kò kọlà ni, kò sí èyí tí ó ṣe pataki. Ohun tí ó ṣe pataki ni pípa àwọn òfin Ọlọrun mọ́. Kí olukuluku wà ní ipò tí ó wà nígbà tí a pè é láti di onigbagbọ. Ẹrú ni ọ́ nígbà tí a fi pè ọ́? Má ṣe gbé e lékàn. Ṣugbọn bí o bá ní anfaani láti di òmìnira, lo anfaani rẹ. Nítorí ẹrú tí a pè láti di onigbagbọ di òmìnira lọ́dọ̀ Oluwa. Bákan náà ni, ẹni òmìnira tí a pè láti di onigbagbọ di ẹrú Kristi. Iyebíye ni Ọlọrun rà yín. Ẹ má ṣe di ẹrú eniyan mọ́. Ẹ̀yin ará, ipòkípò tí olukuluku bá wà tí a bá fi pè é, níbẹ̀ ni kí ó máa wà níwájú Ọlọrun. N kò ní àṣẹ kan láti ọ̀dọ̀ Oluwa láti pa fún àwọn wundia. Ṣugbọn mò ń sọ ohun tí mo rò gẹ́gẹ́ bí ẹni tí Oluwa ti ṣàánú fún, tí eniyan sì lè gbẹ́kẹ̀lé. Mo rò pé ohun tí ó dára ni pé kí eniyan má ṣe kúrò ní ipò tí ó wà, nítorí àkókò ìpọ́njú ni àkókò yìí. Bí o bá ti gbé iyawo, má ṣe wá ọ̀nà láti kọ aya rẹ. Bí o bá sì ti kọ aya rẹ, má ṣe wá ọ̀nà láti tún gbé iyawo. Ṣugbọn bí o bá gbeyawo, kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀. Bí wundia náà bá sì lọ́kọ, kò dẹ́ṣẹ̀. Ṣugbọn irú àwọn bẹ́ẹ̀ yóo ní ìpọ́njú ní ti ara. Bẹ́ẹ̀ ni n kò sì fẹ́ kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ si yín. Ẹ̀yin ará, ohun tí mò ń sọ nìyí. Àkókò tí ó kù fún wa kò gùn. Ninu èyí tí ó kù, kí àwọn tí wọ́n ní iyawo ṣe bí ẹni pé wọn kò ní. Kí àwọn tí ń sunkún máa ṣe bí ẹni pé wọn kò sunkún. Kí àwọn tí ń yọ̀ máa ṣe bí ẹni pé wọn kò yọ̀. Kí àwọn tí ń ra nǹkan máa ṣe bí ẹni pé kì í ṣe tiwọn ni ohun tí wọ́n ní. Kí àwọn tí ń lo dúkìá ayé máa lò ó láì dara dé e patapata. Nítorí bí ayé yìí ti ń rí yìí, ó ń kọjá lọ. Ṣugbọn mo fẹ́ rí i pé ẹ kò ní ìpayà kan tí yóo mú ọkàn yín wúwo. Ẹni tí kò bá ní iyawo yóo máa páyà nípa nǹkan Oluwa, yóo máa wá ọ̀nà láti ṣe ohun tí ó wu Oluwa. Ṣugbọn ẹni tí ó bá gbeyawo yóo máa páyà nípa nǹkan ti ayé yìí, yóo máa wá ọ̀nà láti tẹ́ iyawo rẹ̀ lọ́rùn; ọkàn rẹ̀ yóo pín sí meji. Obinrin tí kò bá lọ́kọ tabi obinrin tí ó bá jẹ́ wundia yóo máa páyà nípa nǹkan ti Oluwa, yóo máa wá ọ̀nà tí yóo fi ya ara ati ọkàn rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Oluwa. Ṣugbọn obinrin tí ó bá ní ọkọ yóo máa páyà nípa àwọn nǹkan ayé, yóo máa wá ọ̀nà láti tẹ́ ọkọ rẹ̀ lọ́rùn. Fún ire ara yín ni mo fi ń sọ èyí fun yín, kì í ṣe láti dín òmìnira yín kù. Ohun tí mò ń fẹ́ ni pé kí ẹ lè gbé irú ìgbé-ayé tí ó yẹ, kí ẹ lè fi gbogbo ara ṣe iṣẹ́ Oluwa, láìwo ọ̀tún tabi òsì. Ṣugbọn bí ọkunrin kan bá rò pé òun ń ṣe ohun tí kò tọ́ pẹlu wundia àfẹ́sọ́nà rẹ̀, tí wundia náà bá ti dàgbà tó, tí ọkunrin náà kò bá lè mú ara dúró, kí ó ṣe igbeyawo bí ó bá fẹ́. Ẹ̀ṣẹ̀ kọ́. Kí wọ́n ṣe igbeyawo. Ṣugbọn ẹni tí ó bá pinnu ninu ọkàn rẹ̀, tí kò sí ìdí tí ó fi gbọdọ̀ ṣe igbeyawo, bí ó bá lè kó ara rẹ̀ ní ìjánu, tí ó sì ti pinnu ní ọkàn ara rẹ̀ pé òun yóo jẹ́ kí wundia òun wà bí ó ti wà, nǹkan dáradára ni ó ṣe. Ní gbolohun kan, ẹni tí ó bá gbé wundia rẹ̀ ní iyawo kò ṣe nǹkan burúkú. Ṣugbọn ẹni tí kò bá gbé e ní iyawo ni ó ṣe ohun tí ó dára jùlọ. A ti so obinrin pọ̀ mọ́ ọkọ rẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ rẹ̀ bá wà láàyè. Ṣugbọn bí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó ní òmìnira láti tún ní ọkọ mìíràn tí ó bá fẹ́. Ṣugbọn onigbagbọ nìkan ní ó lè fẹ́. Ṣugbọn mo rò pé ó sàn fún un pupọ jùlọ tí ó bá dá wà. Mo sì rò pé èmi náà ní Ẹ̀mí Ọlọrun. Ó wá kan ọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí a fi rúbọ fún oriṣa. A mọ̀ pé, “Gbogbo wa ni a ní ìmọ̀,” bí àwọn kan ti ń wí. Ṣugbọn irú ìmọ̀ yìí a máa mú kí eniyan gbéraga, ṣugbọn ìfẹ́ ní ń mú kí eniyan dàgbà. Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun mọ nǹkankan, irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò tíì mọ̀ tó bí ó ti yẹ. Ṣugbọn bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ràn Ọlọrun, òun ni Ọlọrun mọ̀ ní ẹni tirẹ̀. Nítorí náà nípa oúnjẹ tí a fi rúbọ fún oriṣa, a mọ̀ pé oriṣa kò jẹ́ nǹkankan ninu ayé. Ati pé kò sí Ọlọrun mìíràn àfi ọ̀kan ṣoṣo. Nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan tí à ń pè ní oriṣa wà, ìbáà ṣe ní ọ̀run tabi ní ayé, gẹ́gẹ́ bí oriṣa ti pọ̀, tí “àwọn oluwa” tún pọ̀, ṣugbọn ní tiwa, Ọlọrun kan ni ó wà, tíí ṣe Baba, lọ́dọ̀ ẹni tí gbogbo nǹkan ti wá, ati lọ́dọ̀ ẹni tí àwa ń lọ. Oluwa kan ni ó wà. Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí a dá gbogbo nǹkan, nípasẹ̀ rẹ̀ ni a sì ti dá àwa náà. Ṣugbọn kì í ṣe gbogbo eniyan ni ó ní ìmọ̀ yìí. Nítorí àwọn mìíràn wà tí èèwọ̀ nípa ìbọ̀rìṣà ti mọ́ lára tóbẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé, bí wọn bá jẹ irú oúnjẹ yìí, bí ìgbà tí wọn ń bọ̀rìṣà ni. Nítorí wọn kò ní ẹ̀rí ọkàn tí ó lágbára, jíjẹ oúnjẹ bẹ́ẹ̀ jẹ́ àbùkù fún wọn. Kì í ṣe oúnjẹ ni yóo mú wa dé iwájú Ọlọrun. Bí a kò bá jẹ, kò bù wá kù, bí a bá sì jẹ, kò mú kí á sàn ju bí a ti rí tẹ́lẹ̀ lọ. Ṣugbọn ẹ ṣọ́ra kí òmìnira yín má di ohun tí yóo gbé àwọn aláìlera ṣubú. Nítorí bí ẹnìkan tí ẹ̀rí-ọkàn rẹ̀ kò bá lágbára bá rí ìwọ tí o ní ìmọ̀ tí ò ń jẹun ní ilé oriṣa, ǹjẹ́ òun náà kò ní fi ìgboyà wọ inú ilé oriṣa lọ jẹun? Àyọrísí rẹ̀ ni pé ìmọ̀ tìrẹ mú ìparun bá ẹni tí ó jẹ́ aláìlera, arakunrin tí Kristi ti ìtorí tirẹ̀ kú. Ẹ̀ ń fi bẹ́ẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ sí àwọn arakunrin yín tí ó jẹ́ aláìlera, ẹ̀ ń dá ọgbẹ́ sí ọkàn wọn, ẹ sì ń fi bẹ́ẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ sí Kristi. Nítorí náà, bí ọ̀rọ̀ oúnjẹ ni yóo bá gbé arakunrin mi ṣubú, n kò ní jẹ ẹran mọ́ laelae, kí n má baà ṣe ohun tí yóo gbé arakunrin mi ṣubú. Ṣebí mo ní òmìnira? Ṣebí aposteli ni mí? Ṣebí mo ti rí Jesu Oluwa wa sójú? Ṣebí àyọrísí iṣẹ́ mi ninu Oluwa ni yín? Bí àwọn ẹlòmíràn kò bá tilẹ̀ gbà mí bí aposteli, ẹ̀yin gbọdọ̀ gbà mí ni, nítorí èdìdì iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi ninu Kristi ni ẹ jẹ́. Ìdáhùn mi nìyí fún àwọn tí wọn ń rí wí sí mi. Ṣé a kò ní ẹ̀tọ́ láti jẹ ati láti mu ni? Ṣé a kò ní ẹ̀tọ́ láti máa mú aya lọ́wọ́ ninu ìrìn àjò wa gẹ́gẹ́ bí àwọn aposteli yòókù ati àwọn arakunrin Oluwa ati Peteru? Àbí èmi ati Banaba nìkan ni a níláti máa ṣiṣẹ́ bọ́ ara wa? Ta ló jẹ́ ṣe iṣẹ́ ọmọ-ogun tí yóo tún máa bọ́ ara rẹ̀? Ta ló jẹ́ dá oko láì má jẹ ninu èso rẹ̀? Ta ló jẹ́ máa tọ́jú aguntan láìmu ninu wàrà aguntan tí ó ń tọ́jú? Kì í ṣe àpẹẹrẹ ti eniyan nìkan ni mo fi ń sọ nǹkan wọnyi. Ṣebí òfin náà sọ nípa nǹkan wọnyi. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ ninu Òfin Mose pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ di ẹnu mààlúù tí o fi ń ṣiṣẹ́ lóko ọkà.” Ǹjẹ́ nítorí mààlúù ni Ọlọrun ṣe sọ èyí? Tabi kò dájú pé nítorí tiwa ni ó ṣe sọ ọ́? Dájúdájú nítorí tiwa ni. Nítorí ó yẹ kí ẹni tí ń roko kí ó máa roko pẹlu ìrètí láti pín ninu ìkórè oko, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹni tí ó ń pa ọkà ní ìrètí láti pín ninu ọkà náà. Nígbà tí a fúnrúgbìn nǹkan ẹ̀mí fun yín, ṣé ó pọ̀jù pé kí á kórè nǹkan ti ara lọ́dọ̀ yín? Bí àwọn ẹlòmíràn bá ní ẹ̀tọ́ láti jẹ lára yín, ṣé ẹ̀tọ́ tiwa kò ju tiwọn lọ? Ṣugbọn a kò lo anfaani tí a ní yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀ à ń fara da ohun gbogbo kí á má baà fa ìdínà fún ìyìn rere Kristi. Ẹ kò mọ̀ pé àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ninu Tẹmpili a máa jẹ lára ẹbọ, ati pé àwọn tí ń ṣiṣẹ́ níbi pẹpẹ ìrúbọ a máa pín ninu nǹkan ìrúbọ tí ó wà lórí pẹpẹ? Bẹ́ẹ̀ gan-an ni Oluwa pàṣẹ pé kí àwọn tí ó ń waasu ìyìn rere máa jẹ láti inú iṣẹ́ ìyìn rere. Ṣugbọn n kò lo anfaani yìí rí. Kì í ṣe pé kí n lè lo anfaani yìí ni mo ṣe ń sọ ohun tí mò ń sọ yìí. Nítorí ó yá mi lára kí ń kúkú kú jù pé kí ẹnikẹ́ni wá sọ ọ̀nà ìṣògo mi di asán lọ. Nítorí bí mo bá ń waasu ìyìn rere, kì í ṣe ohun tí mo lè máa fi ṣògo. Nítorí dandan ni ó jẹ́ fún mi. Bí n kò bá waasu ìyìn rere, mo gbé! Nítorí bí ó bá jẹ́ pé èmi fúnra mi ni mo yàn láti máa ṣe iṣẹ́ yìí, mo ní ẹ̀tọ́ láti retí èrè níbẹ̀. Ṣugbọn tí ó bá jẹ́ dandan ni mo fi ń ṣe é, iṣẹ́ ìríjú tí a fi sí ìtọ́jú mi ni. Kí wá ni èrè mi? Mo ní ìtẹ́lọ́rùn pé mò ń waasu ìyìn rere lọ́fẹ̀ẹ́, n kò lo anfaani tí ó tọ́ sí mi ninu iṣẹ́ ìyìn rere. Nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òmìnira ni mo wà, tí n kò sì sí lábẹ́ ẹnìkan, sibẹ mo sọ ara mi di ẹrú gbogbo eniyan kí n lè mú ọpọlọpọ wọn wá sọ́dọ̀ Jesu. Nígbà tí mo bá wà láàrin àwọn Juu, èmi a máa di Juu kí n lè jèrè wọn. Nígbà tí mo bá wà láàrin àwọn tí ó gba ètò ti Òfin Mose, èmi a máa fi ara mi sábẹ́ Òfin Mose, kí n lè jèrè àwọn tí ó gba ètò ti Òfin, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò gba ètò ti Òfin Mose fúnra mi. Nígbà tí mo bá wà láàrin àwọn tí kò gba ètò ti Òfin Mose, èmi a máa fi ara mi sí ipò wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ka òfin Ọlọrun sí, pàápàá jùlọ òfin Kristi. Èmi a máa ṣe bẹ́ẹ̀ kí n lè jèrè àwọn tí kò gba ètò ti Òfin Mose. Nígbà tí mo bá wà láàrin àwọn aláìlera, èmi a di aláìlera, kí n lè jèrè àwọn aláìlera. Èmi a máa sọ ara mi di gbogbo nǹkan fún gbogbo eniyan, kí n lè gba àwọn kan ninu wọn là lọ́nà kan tabi lọ́nà mìíràn. Èmi a máa ṣe gbogbo nǹkan wọnyi nítorí ti ìyìn rere, kí n lè ní ìpín ninu ibukun rẹ̀. Ṣebí ẹ mọ̀ pé gbogbo àwọn tí ń sáré ìje ni ó ń sáré, ṣugbọn ẹnìkan ṣoṣo níí gba ẹ̀bùn. Ẹ sáré ní ọ̀nà tí ẹ óo fi rí ẹ̀bùn gbà. Nítorí gbogbo àwọn tí ń sáré ìje a máa kó ara wọn ní ìjánu. Wọ́n ń ṣe èyí kí wọ́n lè gba adé tí yóo bàjẹ́. Ṣugbọn adé tí kò lè bàjẹ́ ni tiwa. Nítorí náà, aré tí èmi ń sá kì í ṣe ìsákúsàá láìní ète. Èmi kì í máa kan ẹ̀ṣẹ́ tèmi ní ìkànkukàn, bí ẹni tí ń kan afẹ́fẹ́ lásán lẹ́ṣẹ̀ẹ́. Ṣugbọn mò ń fi ìyà jẹ ara mi, mò ń kó ara mi ní ìjánu. Ìdí ni pé nígbà tí mo bá ti waasu fún àwọn ẹlòmíràn tán, kí èmi alára má baà di ẹni tí kò ní yege ninu iré-ìje náà. Ẹ̀yin ará, ẹ má gbàgbé pé gbogbo àwọn baba wa ni wọ́n wà lábẹ́ ìkùukùu. Gbogbo wọn ni wọ́n la òkun kọjá. Gbogbo wọn ni wọ́n ṣe ìrìbọmi ninu ìkùukùu ati ninu òkun, kí wọ́n lè di ọmọ ẹ̀yìn Mose. Gbogbo wọn ni wọ́n jẹ oúnjẹ ẹ̀mí kan náà. Gbogbo wọn ni wọ́n mu omi ẹ̀mí kan náà, nítorí wọ́n mu omi tí ó jáde láti inú òkúta ẹ̀mí tí ó ń tẹ̀lé wọn. Òkúta náà ni Kristi. Ṣugbọn sibẹ inú Ọlọrun kò dùn sí ọpọlọpọ ninu wọn, nítorí ọpọlọpọ wọn ni wọ́n kú dànù káàkiri ninu aṣálẹ̀. Àwọn nǹkan wọnyi jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa, pé kí á má ṣe kó nǹkan burúkú lé ọkàn, gẹ́gẹ́ bí àwọn ti kó o lé ọkàn. Kí ẹ má sì di abọ̀rìṣà bí àwọn mìíràn ninu wọn. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Àwọn eniyan náà jókòó láti jẹ ati láti mu, wọ́n sì dìde láti ṣe àríyá.” Bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè bí àwọn mìíràn ninu wọn ti ṣe àgbèrè, tí ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹẹdogun (23,000) eniyan fi kú ní ọjọ́ kan. Bẹ́ẹ̀ ni kí á má ṣe dán Oluwa wò, bí àwọn mìíràn ninu wọn ti dán an wò, tí ejò fi ṣán wọn pa. Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe kùn bí àwọn mìíràn ninu wọn ṣe kùn, tí Apani sì pa wọ́n. Gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn yìí jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa. A kọ wọ́n sílẹ̀ kí ó lè jẹ́ ìkìlọ̀ fún wa, àwa tí a wà ní ìgbà ìkẹyìn. Nítorí náà, ẹni tí ó bá rò pé òun dúró kí ó ṣọ́ra kí ó má baà ṣubú. Kò sí ìdánwò kan tí ó dé ba yín bíkòṣe irú èyí tí ó wọ́pọ̀ láàrin eniyan. Ṣugbọn Ọlọrun tó gbẹ́kẹ̀lé, kò ní jẹ́ kí ẹ rí ìdánwò tí ó ju èyí tí ẹ lè fara dà lọ. Ṣugbọn ní àkókò ìdánwò, yóo pèsè ọ̀nà àbáyọ, yóo sì mú kí ẹ lè fara dà á. Nítorí náà, ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, ẹ sá fún ìbọ̀rìṣà. Mò ń ba yín sọ̀rọ̀ bí ọlọ́gbọ́n. Ẹ̀yin fúnra yín náà, ẹ gba ohun tí mò ń sọ rò. Ife ibukun tí à ń dúpẹ́ fún, ṣebí àjọpín ninu ẹ̀jẹ̀ Kristi ni. Burẹdi tí a bù, ṣebí àjọpín ninu ara Kristi ni. Nítorí burẹdi kan ni ó wà, ninu ara kan yìí ni gbogbo wa sì wà, nítorí ninu burẹdi kan ni gbogbo wa ti ń jẹ. Ẹ ṣe akiyesi ìṣe àwọn ọmọ Israẹli. Ṣebí àwọn tí ń jẹ ẹbọ ń jẹ ninu anfaani lílo pẹpẹ ìrúbọ fún ìsìn Ọlọrun? Nítorí náà, ṣé ohun tí mò ń sọ ni pé ohun tí a fi rúbọ fún oriṣa jẹ́ nǹkan? Tabi pé oriṣa jẹ́ nǹkan? Rárá o! Ohun tí mò ń sọ ni pé àwọn nǹkan tí àwọn abọ̀rìṣà fi ń rúbọ, ẹ̀mí burúkú ni wọ́n fi ń rúbọ sí, kì í ṣe Ọlọrun. N kò fẹ́ kí ẹ ní ìdàpọ̀ pẹlu àwọn ẹ̀mí burúkú. Ẹ kò lè mu ninu ife Oluwa tán kí ẹ tún lọ mu ninu ife ti ẹ̀mí burúkú. Ẹ kò lè jẹ ninu oúnjẹ orí tabili Oluwa, kí ẹ tún lọ jẹ ninu oúnjẹ orí tabili ẹ̀mí burúkú. Àbí a fẹ́ mú Oluwa jowú ni bí? Àbí a lágbára jù ú lọ ni? Lóòótọ́, “Ohun tí a bá fẹ́ ni a lè ṣe,” bí àwọn kan ti ń wí. Ṣugbọn kì í ṣe gbogbo nǹkan ni ó ń ṣe eniyan ní anfaani. “Ohun tí a bá fẹ́ ni a lè ṣe.” Ṣugbọn kì í ṣe gbogbo nǹkan tí a lè ṣe ni ó ń mú ìdàgbà wá. Kí ẹnikẹ́ni má ṣe máa wá ire ti ara rẹ̀ bíkòṣe ire ẹnìkejì rẹ̀. Kí ẹ jẹ ohunkohun tí ẹ bá rà ní ọjà láì wádìí ohunkohun kí ẹ̀rí-ọkàn yín lè mọ́; “Nítorí Oluwa ni ó ni ayé ati gbogbo nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀.” Bí ẹnìkan ninu àwọn alaigbagbọ bá pè yín wá jẹun, tí ẹ bá gbà láti lọ, ẹ jẹ ohunkohun tí ó bá gbé kalẹ̀ níwájú yín láì wádìí ohunkohun, kí ẹ̀rí-ọkàn yín lè mọ́. Ṣugbọn bí ẹnìkan bá sọ fun yín pé, “A ti fi oúnjẹ yìí ṣe ìrúbọ,” ẹ má jẹ ẹ́, nítorí ẹni tí ó sọ bẹ́ẹ̀ ati nítorí ẹ̀rí-ọkàn. Kì í ṣe ẹ̀rí-ọkàn tiyín ni mò ń sọ bíkòṣe ẹ̀rí-ọkàn ti ẹni tí ó pe akiyesi yín sí oúnjẹ náà. Kí ló dé tí yóo fi jẹ́ pé ẹ̀rí-ọkàn ẹlòmíràn ni yóo máa sọ bí n óo ti ṣe lo òmìníra mi? Bí mo bá jẹ oúnjẹ pẹlu ọpẹ́ sí Ọlọrun, ẹ̀tọ́ wo ni ẹnìkan níláti bá mi wí fún ohun tí mo ti dúpẹ́ fún? Nítorí náà, ìbáà jẹ́ pé ẹ̀ ń jẹ ni, tabi pé ẹ̀ ń mu ni, ohunkohun tí ẹ bá ń ṣe, ẹ máa ṣe é fún ògo Ọlọrun. Ẹ má ṣe jẹ́ ohun ìkọsẹ̀ fún àwọn Juu tabi fún àwọn tí kì í ṣe Juu tabi fún ìjọ Ọlọrun. Ní tèmi, mò ń gbìyànjú láti ṣe ohun tí ó wu gbogbo eniyan ní gbogbo ọ̀nà. Kì í ṣe ohun tí ó jẹ́ anfaani tèmi ni mò ń wá, bíkòṣe ohun tí ó jẹ́ anfaani ọpọlọpọ eniyan, kí á lè gbà wọ́n là. Ẹ máa fara wé mi bí èmi náà tí ń fara wé Kristi. Mo yìn yín nítorí pé ẹ̀ ń ranti mi nígbà gbogbo, ati pé ẹ kò jẹ́ kí àwọn ẹ̀kọ́ tí mo fi kọ yín látijọ́ bọ́ lọ́wọ́ yín. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé Kristi ni orí fún olukuluku ọkunrin, ọkunrin ni orí fún obinrin, Ọlọrun wá ni orí Kristi. Ọkunrin tí ó bá ń gbadura tabi tí ó bá ń waasu tí ó bo orí fi àbùkù kan orí rẹ̀. Ṣugbọn obinrin tí ó bá ń gbadura tabi tí ó bá ń waasu láì bo orí rẹ̀ fi àbùkù kan orí rẹ̀. Ó dàbí kí ó kúkú fá orí rẹ̀. Nítorí bí obinrin kò bá bo orí, kí ó kúkú gé irun rẹ̀ mọ́lẹ̀. Ṣugbọn tí ó bá jẹ́ ìtìjú fún obinrin láti gé irun rẹ̀ mọ́lẹ̀ tabi láti fá orí rẹ̀ a jẹ́ pé ó níláti bo orí rẹ̀. Nítorí kò tọ́ kí ọkunrin bo orí rẹ̀, nítorí àwòrán ati ògo Ọlọrun ni. Ṣugbọn ògo ọkunrin ni obinrin. Nítorí ọkunrin kò wá láti ara obinrin; obinrin ni ó wá láti ara ọkunrin. Ati pé a kò dá ọkunrin nítorí obinrin, obinrin ni a dá nítorí ọkunrin. Nítorí èyí, ó yẹ kí obinrin ní àmì àṣẹ ní orí nítorí àwọn angẹli. Ṣugbọn ṣá, ninu Oluwa, bí obinrin ti nílò ọkunrin, bẹ́ẹ̀ ni ọkunrin nílò obinrin. Nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé láti ara ọkunrin ni obinrin ti wá, láti inú obinrin ni ọkunrin náà sì ti wá. Ṣugbọn ohun gbogbo ti ọ̀dọ̀ Oluwa wá. Ẹ̀yin náà ẹ ro ọ̀rọ̀ ọ̀hún wò láàrin ara yín. Ǹjẹ́ ó bójú mu pé kí obinrin gbadura sí Ọlọrun láì bo orí? Mo ṣebí ìṣe ẹ̀dá pàápàá kọ yín pé tí ọkunrin bá jẹ́ kí irun rẹ̀ gùn, ó fi àbùkù kan ara rẹ̀; bẹ́ẹ̀ sì ni pé ohun ìyìn ni ó jẹ́ fún obinrin tí ó bá jẹ́ kí irun rẹ̀ gùn. Nítorí a fi irun gígùn fún obinrin láti bò ó lórí. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ máa jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí, kí ẹ mọ̀ pé ní tiwa, a kò ní oríṣìí àṣà mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ninu àwọn ìjọ Ọlọrun. Nígbà tí mò ń sọ èyí, nǹkankan wà tí n kò yìn yín fún, nítorí nígbà tí ẹ bá péjọ, ìpéjọpọ̀ yín ń ṣe ibi ju rere lọ. Nítorí, ní ọ̀nà kinni, mo gbọ́ pé nígbà tí ẹ bá péjọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìjọ, ìyapa a máa wà láàrin yín. Mo gbàgbọ́ pé òtítọ́ wà ninu ìròyìn yìí. Nítorí ìyapa níláti wà láàrin yín, kí àwọn tí ń ṣe ẹ̀tọ́ láàrin yín lè farahàn. Nítorí èyí, nígbà tí ẹ bá péjọ sí ibìkan náà, kì í ṣe Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa ni ẹ̀ ń jẹ. Nítorí pé ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu yín níí máa kánjú jẹun, ebi a máa pa àwọn kan nígbà tí àwọn mìíràn ti mu ọtí lámuyó! Ṣé ẹ kò ní ilé tí ẹ ti lè máa jẹ, kí ẹ máa mu ni? Àbí ẹ fẹ́ kó ẹ̀gàn bá ìjọ Ọlọrun ni? Ẹ fẹ́ dójú ti àwọn aláìní, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Kí ni kí n sọ fun yín? Ṣé kí n máa yìn yín ni? Rárá o! N kò ní yìn yín fún èyí. Nítorí láti ọ̀dọ̀ Oluwa ni mo ti gba ohun tí mo fi kọ yín, pé ní alẹ́ ọjọ́ tí a fi Jesu Oluwa lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, ó mú burẹdi, lẹ́yìn tí ó ti dúpẹ́ tán, ó bù ú, ó ní, “Èyí ni ara mi tí ó wà fun yín. Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” Bákan náà ni ó mú ife lẹ́yìn oúnjẹ, ó ní, “Èyí ni ife ti majẹmu titun tí a fi ẹ̀jẹ̀ mi dá. Nígbàkúùgbà tí ẹ bá ń mu ún, ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” Nítorí nígbàkúùgbà tí ẹ bá ń jẹ burẹdi yìí, tí ẹ sì ń mu ninu ife yìí, ẹ̀ ń kéde ikú Oluwa títí yóo fi dé. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń jẹ burẹdi, tabi tí ó ń mu ninu ife Oluwa láìyẹ jẹ̀bi ìlòkulò ara ati ẹ̀jẹ̀ Oluwa. Kí olukuluku yẹ ara rẹ̀ wò kí ó tó jẹ ninu burẹdi, kí ó sì tó mu ninu ife Oluwa. Nítorí ẹni tí ó bá ń jẹ, tí ó ń mu láìmọ ìyàtọ̀ tí ó wà ninu ara Kristi, ìdájọ́ ni ó ń jẹ, tí ó sì ń mu, lórí ara rẹ̀. Nítorí èyí ni ọpọlọpọ ninu yín ṣe di aláìlera ati ọlọ́kùnrùn, tí ọpọlọpọ tilẹ̀ ti kú. Ṣugbọn tí a bá ti yẹ ara wa wò, a kò ní dá wa lẹ́jọ́. Ṣugbọn bí a bá bọ́ sinu ìdájọ́ Oluwa, ó fi ń bá wa wí ni, kí ó má baà dá wa lẹ́bi pẹlu àwọn yòókù. Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ bá péjọ láti jẹun, ẹ máa dúró de ara yín. Bí ebi bá ń pa ẹnikẹ́ni, kí ó jẹun kí ó tó kúrò ní ilé, kí ìpéjọpọ̀ yín má baà jẹ́ ìdálẹ́bi fun yín. Nígbà tí mo bá dé, n óo ṣe ètò nípa àwọn nǹkan tí ó kù. Ẹ̀yin ará, n kò fẹ́ kí nǹkan nípa ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ ṣókùnkùn si yín. Ẹ mọ̀ pé nígbà tí ẹ jẹ́ aláìmọ Ọlọrun, ẹ̀ ń bọ oriṣa tí kò lè fọhùn. À ń tì yín síwá sẹ́yìn. Nítorí náà, mò ń fi ye yín pé kò sí ẹni tí ó lè máa fi agbára Ẹ̀mí Ọlọrun sọ̀rọ̀ tí ó jẹ́ fi Jesu gégùn-ún, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó lè wí pé, “Jesu ni Oluwa,” láìjẹ́ pé Ẹ̀mí Mímọ́ bá darí rẹ̀. Oríṣìíríṣìí ni ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ ṣugbọn láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí kan náà ni wọ́n ti ń wá. Oríṣìíríṣìí iṣẹ́ iranṣẹ ni ó wà, ṣugbọn Oluwa kan náà ni à ń sìn. Oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ni ó wà, ṣugbọn Ọlọrun kan náà ní ń ṣe ohun gbogbo ninu gbogbo eniyan. Iṣẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́ ń farahàn ninu olukuluku wa fún ire gbogbo wa. Nítorí láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ ni a ti fún ẹnìkan ní ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n, a sì fún ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ ìmọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí kan náà. Ẹlòmíràn ní igbagbọ, láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí kan náà, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn láti ṣe ìwòsàn, láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí kan náà; ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn àtiṣe iṣẹ́ ìyanu, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn iwaasu, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn òye láti mọ ìyàtọ̀ láàrin ẹ̀mí òtítọ́ ati ẹ̀mí èké, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn láti fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn láti túmọ̀ àwọn èdè àjèjì. Ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí kan ṣoṣo ni gbogbo ẹ̀bùn wọnyi ti wá; bí ó sì ti wù ú ni ó pín wọn fún ẹnìkọ̀ọ̀kan. Nítorí gẹ́gẹ́ bí ara ti jẹ́ ọ̀kan, tí ó ní ọpọlọpọ ẹ̀yà, bí gbogbo àwọn ẹ̀yà ara ti pọ̀ tó, sibẹ tí ara jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo, bẹ́ẹ̀ ni Kristi rí. Nítorí nípa Ẹ̀mí kan ni gbogbo wa fi ṣe ìrìbọmi tí a fi di ara kan, ìbáà ṣe pé a jẹ́ Juu tabi Giriki, à báà jẹ́ ẹrú tabi òmìnira, ninu Ẹ̀mí kan ṣoṣo ni a ti fún gbogbo wa mu. Nítorí kì í ṣe ẹ̀yà kan ṣoṣo ni ara ní; wọ́n pọ̀. Bí ẹsẹ̀ bá sọ pé, “Èmi kì í ṣe ọwọ́, nítorí náà èmi kò sí ninu ara,” èyí kò wí pé kì í tún ṣe ẹ̀yà ara mọ́. Bí etí bá sọ pé, “Èmi kì í ṣe ojú, nítorí náà èmi kò sí ninu ara,” kò wí pé kí ó má ṣe ẹ̀yà ara mọ́. Bí gbogbo ara bá jẹ́ ojú, báwo ni yóo ti ṣe gbọ́ràn? Bí gbogbo ara bá jẹ́ etí, báwo ni yóo ti ṣe gbóòórùn? Ṣugbọn lóòótọ́ ni, Ọlọrun fi àwọn ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan sí ipò wọn bí ó ti wù ú. Bí ó bá jẹ́ pé ẹ̀yà kan ṣoṣo ni gbogbo ara ní, níbo ni ara ìbá wà? Bí ó ti wà yìí, ẹ̀yà pupọ ni ó ní, ṣugbọn ara kan ṣoṣo ni. Ojú kò lè wí fún ọwọ́ pé, “N kò nílò rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni orí kò lè wí fún ẹsẹ̀ pé, “N kò nílò yín.” Kàkà bẹ́ẹ̀ àwọn ẹ̀yà ara tí kò lágbára jẹ́ àwọn tí a kò lè ṣe aláìní. Àwọn ẹ̀yà mìíràn tí a rò pé wọn kò dùn ún wò ni à ń dá lọ́lá jù. Àwọn ẹ̀yà ara tí kò dùn ún wò ni à ń yẹ́ sí jùlọ. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ẹ̀yà ara tí ó dùn ún wò kò nílò ọ̀ṣọ́ lọ títí. Ọlọrun ti ṣe ètò àwọn ẹ̀yà ara ní ọ̀nà tí ó fi fi ọlá fún àwọn ẹ̀yà tí kò dùn ún wò, kí ó má baà sí ìyapa ninu ara, ṣugbọn kí gbogbo àwọn ẹ̀yà ara lè máa ṣe aájò kan náà fún ara wọn. Bí ẹ̀yà ara kan bá ń jẹ ìrora, gbogbo àwọn ẹ̀yà yòókù níí máa bá a jẹ ìrora. Bí ara bá tu ẹ̀yà kan, gbogbo àwọn ẹ̀yà yòókù ni yóo máa bá a yọ̀. Ẹ̀yin ni ara Kristi, ẹ̀yà ara rẹ̀ ni ẹnìkọ̀ọ̀kan yín. Oríṣìíríṣìí eniyan ni Ọlọrun yàn ninu ìjọ: àwọn kinni ni àwọn aposteli, àwọn keji, àwọn wolii; àwọn kẹta, àwọn olùkọ́ni; lẹ́yìn náà, àwọn oníṣẹ́ ìyanu, kí ó tó wá kan àwọn tí wọ́n ní ẹ̀bùn láti ṣe ìwòsàn tabi àwọn tí ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ẹlòmíràn, tabi àwọn tí wọ́n ní ẹ̀bùn láti darí ètò iṣẹ́ ìjọ, ati àwọn tí wọ́n ní ẹ̀bùn láti sọ èdè àjèjì. Gbogbo yín ni aposteli bí? Àbí gbogbo yín ni wolii? Ṣé gbogbo yín ni olùkọ́ni? Àbí gbogbo yín ni ẹ lè ṣe iṣẹ́ ìyanu? Kì í ṣe gbogbo yín ni ẹ ní ẹ̀bùn kí á ṣe ìwòsàn. Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe gbogbo yín ni ẹ lè sọ èdè àjèjì. Àbí gbogbo yín ni ẹ lè túmọ̀ àwọn èdè àjèjì? Ẹ máa fi ìtara lépa àwọn ẹ̀bùn tí ó ga jùlọ. Ṣugbọn n óo fi ọ̀nà kan tí ó dára jùlọ hàn yín. Ǹ báà lè sọ oríṣìíríṣìí èdè tí eniyan ń fọ̀, kódà kí n tún lè sọ ti àwọn angẹli, bí n kò bá ní ìfẹ́, bí idẹ tí ń dún lásán ni mo rí; mo dàbí páànù tí wọn ń lù, tí ń hanni létí bí agogo. Ǹ báà ní ẹ̀bùn wolii, kí n ní gbogbo ìmọ̀, kí n mọ gbogbo àṣírí ayé, kí n ní igbagbọ tí ó gbóná tóbẹ́ẹ̀ tí ó lè ṣí òkè ní ìdí, tí n kò bá ní ìfẹ́, n kò já mọ́ nǹkankan. Ǹ báà kò gbogbo ohun tí mo ní, kí n fi tọrẹ, kódà kí n fi ara mi rú ẹbọ sísun, bí n kò bá ní ìfẹ́, kò ṣe anfaani kankan fún mi. Ìfẹ́ a máa mú sùúrù, a máa ṣe oore. Ìfẹ́ kì í jowú, kì í ṣe ìgbéraga, bẹ́ẹ̀ ni kì í fọ́nnu. Ìfẹ́ kì í ṣe ohun tí kò tọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì í hùwà ìmọ-tara-ẹni-nìkan. Kì í tètè bínú, bẹ́ẹ̀ ni kì í ka ẹ̀ṣẹ̀ sí eniyan lọ́rùn. Ìfẹ́ kì í fi nǹkan burúkú ṣe ayọ̀, ṣugbọn a máa yọ̀ ninu òtítọ́. Ìfẹ́ a máa fara da ohun gbogbo, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa ní ìrètí ninu ohun gbogbo, a sì máa foríti ohun gbogbo. Ìfẹ́ kò lópin. Ní ti ọ̀rọ̀ wolii, wọn yóo di ohun tí kò wúlò mọ́. Ní ti àwọn èdè àjèjì wọn yóo di ohun tí a kò gbúròó mọ́. Ní ti ìmọ̀, yóo di ohun tí kò wúlò mọ́. Kò sí ẹni tí ó mọ ọ̀ràn ní àmọ̀tán, bẹ́ẹ̀ ni kò sí wolii tí ó ríran, ní àrítán. Ṣugbọn nígbà tí ohun tí ó pé bá dé, àwọn ohun tí kò pé yóo di ohun tí kò wúlò mọ́. Nígbà tí mo wà ní ọmọde, èmi a máa sọ̀rọ̀ bí ọmọde, èmi a máa gbèrò bí ọmọde, ṣugbọn nisinsinyii tí mo ti dàgbà, mo ti pa ìwà ọmọde tì. Nítorí nisinsinyii, à ń ríran bàìbàì ninu dígí. Ṣugbọn nígbà tí ó bá yá, ojú yóo kojú, a óo sì ríran kedere. Nisinsinyii, kò sí ohunkohun tí mo mọ̀ ní àmọ̀tán. Ṣugbọn nígbà náà, n óo ní ìmọ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti mọ̀ mí. Ní gbolohun kan, àwọn nǹkan mẹta ni ó wà títí lae; igbagbọ, ìrètí, ati ìfẹ́; ṣugbọn èyí tí ó tóbi jù ninu wọn ni ìfẹ́. Ẹ máa lépa ìfẹ́. Ṣugbọn ẹ tún máa tiraka láti ní Ẹ̀mí Mímọ́, pàápàá jùlọ, ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀. Nítorí ẹni tí ó bá ń fi èdè sọ̀rọ̀ kò bá eniyan sọ̀rọ̀, Ọlọrun ni ó ń bá sọ̀rọ̀. Nítorí pé kò sí ẹni tí ó gbọ́ ohun tí ó ń sọ. Ẹ̀mí ni ó gbé e tí ó fi ń sọ ohun àṣírí tí ó ń sọ tí kò yé eniyan. Ṣugbọn ẹni tí ó ń waasu ń bá eniyan sọ̀rọ̀ fún ìdàgbà ti ẹ̀mí, fún ìtùnú, ati ìwúrí. Ẹni tí ó ń fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, ara rẹ̀ nìkan ni ó ń mú dàgbà. Ṣugbọn ẹni tí ó ń waasu ń mú ìjọ dàgbà. Inú mi ìbá dún bí gbogbo yín bá lè máa fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀. Ṣugbọn ohun tí ìbá dùn mọ́ mi ninu jùlọ ni pé kí ẹ lè máa waasu. Ẹni tí ó ń waasu ju ẹni tí ó ń fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀ lọ, àfi bí ó bá túmọ̀ ohun tí ó fi èdè àjèjì sọ, kí ìjọ lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ fún ìdàgbà ẹ̀mí. Ará, ǹjẹ́ bí mo bá wá sọ́dọ̀ yín, tí mò ń fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, anfaani wo ni mo ṣe fun yín? Kò sí, àfi bí mo bá ṣe àlàyé nípa ìfihàn, tabi ìmọ̀, tabi iwaasu, tabi ẹ̀kọ́ tí mo fi èdè àjèjì sọ. Bí àwọn nǹkan tí kò ní ẹ̀mí tí à ń fi kọ orin, bíi fèrè tabi dùùrù, kò bá dún dáradára, ta ni yóo mọ ohùn orin tí wọn ń kọ? Bí ohun tí fèrè ogun bá ń wí kò bá yé eniyan, ta ni yóo palẹ̀ mọ́ fún ogun? Bẹ́ẹ̀ gan-an ni tí ẹ bá ń lo èdè àjèjì, tí ẹ kò lo ọ̀rọ̀ tí ó yé eniyan, báwo ni eniyan yóo ṣe mọ ohun tí ẹ ń sọ? Afẹ́fẹ́ lásán ni ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ sí. Láìsí àní-àní, oríṣìíríṣìí èdè ni ó wà láyé, ṣugbọn kò sí èyí tí kò ní ìtumọ̀ ninu wọn. Nítorí náà, bí n kò bá gbọ́ èdè kan, mo di aláìgbédè lójú ẹni tí ó bá ń sọ èdè náà, òun náà sì di kògbédè lójú mi. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí pẹlu yín. Níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀ ń tiraka láti ní ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, ẹ máa wá àwọn ẹ̀bùn tí yóo mú ìjọ dàgbà. Ìdí rẹ̀ nìyí tí ẹni tí ó ń fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀ fi níláti gbadura fún ẹ̀bùn láti lè túmọ̀ rẹ̀. Bí mo bá ń fi èdè àjèjì gbadura, ẹ̀mí mi ni ó ń gbadura, ṣugbọn n kò lo òye ti inú ara mi nígbà náà. Kí ni kí á wá wí? N óo gbadura bí Ẹ̀mí bá ti darí mi, ṣugbọn n óo kọrin pẹlu òye. Bí o bá ń gbadura ọpẹ́ ní ọkàn rẹ, bí ẹnìkan bá wà níbẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ nǹkan nípa igbagbọ, báwo ni yóo ṣe lè ṣe “Amin” sí adura ọpẹ́ tí ò ń gbà nígbà tí kò mọ ohun tí ò ń sọ? Ọpẹ́ tí ò ń ṣe lè dára ṣugbọn kò mú kí ẹlòmíràn lè dàgbà. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nítorí mò ń sọ ọpọlọpọ èdè àjèjì ju gbogbo yín lọ. Ṣugbọn ninu ìjọ, ó yá mi lára kí n sọ ọ̀rọ̀ marun-un pẹlu òye kí n lè kọ́ àwọn ẹlòmíràn, jù kí n sọ ọ̀rọ̀ kí ilẹ̀ kún ní èdè àjèjì lọ. Ará, ẹ má máa ṣe bí ọmọde ninu èrò yín. Ó yẹ kí ẹ dàbí ọmọde tí kò mọ ibi, ṣugbọn kí ẹ jẹ́ àgbàlagbà ninu èrò yín. Ninu Òfin, ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, Oluwa wí pé, “N óo bá àwọn eniyan yìí sọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn eniyan tí ó ń sọ èdè àjèjì, ati láti ẹnu àwọn àlejò. Sibẹ wọn kò ní gbọ́ràn sí mi lẹ́nu.” Àwọn èdè àjèjì yìí kì í ṣe àmì fún àwọn tí ó gbàgbọ́, bíkòṣe fún àwọn tí kò gbàgbọ́. Nítorí náà, nígbà tí gbogbo ìjọ bá péjọ pọ̀ sí ibìkan náà, tí gbogbo yín bá ń fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, tí àwọn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ nǹkan nípa igbagbọ, tabi àwọn alaigbagbọ bá wọlé, ǹjẹ́ wọn kò ní sọ pé ẹ̀ ń ṣiwèrè ni? Ṣugbọn bí gbogbo yín bá ń sọ àsọtẹ́lẹ̀, bí ẹnìkan tí ó jẹ́ alaigbagbọ tabi ẹnìkan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ nǹkan nípa igbagbọ bá wọlé, yóo gbọ́ ohun tí ó jẹ́ ìbáwí ati ohun tí yóo mú un yẹ ara rẹ̀ wò ninu ọ̀rọ̀ tí ẹ̀ ń sọ. Àwọn ohun ìkọ̀kọ̀ ọkàn rẹ̀ yóo hàn kedere, ni yóo bá dojúbolẹ̀, yóo sì júbà Ọlọrun. Yóo sọ pé, “Dájúdájú Ọlọrun wà láàrin yín.” Ará, kí ni kókó ohun tí à ń sọ? Nígbà tí ẹ bá péjọ pọ̀, bí ẹnìkan bá ní orin, tí ẹnìkan ní ẹ̀kọ́, tí ẹnìkan ní ìfihàn, tí ẹnìkan ní èdè àjèjì, tí ẹnìkan ní ìtumọ̀ fún èdè àjèjì, ẹ gbọdọ̀ máa ṣe ohun gbogbo fún ìdàgbà ìjọ. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, kí wọ́n má ju meji lọ, tabi ó wá pọ̀jù patapata, kí wọ́n jẹ́ mẹta. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ni kí wọ́n máa sọ̀rọ̀, kí ẹnìkan sì máa túmọ̀ ohun tí wọn ń sọ. Bí kò bá sí ẹni tí yóo ṣe ìtumọ̀, kí ẹni tí ó fẹ́ fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀ dákẹ́ ninu ìjọ. Kí ó máa fi èdè àjèjì bá ara rẹ̀ ati Ọlọrun sọ̀rọ̀. Ẹni meji tabi mẹta ni kí ó ṣe ìsọtẹ́lẹ̀, kí àwọn yòókù máa fi òye bá ohun tí wọn ń sọ lọ. Bí ẹlòmíràn tí ó jókòó ní àwùjọ bá ní ìfihàn, ẹni kinni tí ó ti ń sọ̀rọ̀ níláti dákẹ́. Gbogbo yín lè sọ àsọtẹ́lẹ̀, lọ́kọ̀ọ̀kan, kí gbogbo yín lè rí ẹ̀kọ́ kọ́, kí gbogbo yín lè ní ìwúrí. Àwọn tí ó ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀ níláti lè káwọ́ ara wọn nígbà tí ẹ̀mí bá gbé wọn láti sọ àsọtẹ́lẹ̀. Nítorí Ọlọrun kì í ṣe Ọlọrun ìdàrúdàpọ̀. Ọlọrun alaafia ni. Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ninu gbogbo ìjọ eniyan Ọlọrun, àwọn obinrin gbọdọ̀ panumọ́ ninu ìjọ. A kò gbà wọ́n láyè láti sọ̀rọ̀. Wọ́n níláti wà ní ipò ìtẹríba, gẹ́gẹ́ bí Òfin ti wí. Bí nǹkankan bá wà tí wọ́n fẹ́ mọ̀, kí wọ́n bi àwọn ọkọ wọn ní ilé. Ìtìjú ni fún obinrin láti sọ̀rọ̀ ninu ìjọ. Ṣé ọ̀dọ̀ yín ni ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti kọ́ bẹ̀rẹ̀ ni àbí ẹ̀yin nìkan ni ẹ mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọrun? Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé wolii ni òun tabi pé òun ní agbára Ẹ̀mí, kí olúwarẹ̀ mọ̀ pé àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Oluwa ni ohun tí mo kọ ranṣẹ si yín yìí. Ṣugbọn bí ẹnikẹ́ni kò bá gba ohun tí a wí yìí, a kò gba òun náà. Nítorí náà, ẹ̀yin ará, ẹ máa tiraka láti sọ àsọtẹ́lẹ̀. Ẹ má ka fífi èdè àjèjì sọ̀rọ̀ sí èèwọ̀. Ẹ máa ṣe ohun gbogbo létòlétò, ní ọ̀nà tí ó dára. Ará, mo fẹ́ ran yín létí ọ̀rọ̀ ìyìn rere tí mo fi waasu fun yín, tí ẹ gbà, tí ẹ sì bá dúró. Nípa ìyìn rere yìí ni a fi ń gbà yín là, tí ẹ bá dì mọ́ ọ̀rọ̀ ìyìn rere tí mo fi waasu fun yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ asán ni igbagbọ yín. Nítorí ohun kinni tí ó ṣe pataki jùlọ tí èmi fúnra mi kọ́, tí mo sì fi kọ́ yín ni pé Kristi kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí. Ati pé a sin ín, a sì jí i dìde ní ọjọ́ kẹta, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí. Ó fara han Peteru. Lẹ́yìn náà ó tún fara han àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila. Lẹ́yìn náà ó tún fara han ẹẹdẹgbẹta (500) àwọn onigbagbọ lẹ́ẹ̀kan náà. Ọpọlọpọ ninu wọn wà títí di ìsinsìnyìí, ṣugbọn àwọn mìíràn ti kú. Lẹ́yìn náà, ó fara han Jakọbu, ó sì tún fara han gbogbo àwọn aposteli. Ní ìgbẹ̀yìn-gbẹ́yín gbogbo wọn, ó wá farahàn mí, èmi tí mo dàbí ọmọ tí a bí kí oṣù rẹ̀ tó pé. Nítorí èmi ni mo kéré jùlọ ninu àwọn aposteli. N kò tilẹ̀ yẹ ní ẹni tí wọn ìbá máa pè ní aposteli, nítorí pé mo ṣe inúnibíni sí ìjọ Ọlọrun. Ṣugbọn nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun ni mo jẹ́ ohun tí mo jẹ́. Oore-ọ̀fẹ́ yìí kò sì jẹ́ lásán lórí mí, nítorí mo ṣe akitiyan ju gbogbo àwọn aposteli yòókù lọ. Ṣugbọn kì í ṣe èmi tìkara mi, oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun tí ó wà pẹlu mi ni. Nítorí náà, ìbáà ṣe èmi ni, tabi àwọn aposteli yòókù, bákan náà ni iwaasu wa, bẹ́ẹ̀ sì ni ohun tí ẹ gbàgbọ́. Nígbà tí ó jẹ́ pé, à ń kéde pé Kristi jinde kúrò ninu òkú, báwo ni àwọn kan ninu yín ṣe wá ń wí pé kò sí ajinde òkú? Bí kò bá sí ajinde òkú, a jẹ́ pé a kò jí Kristi dìde. Bí a kò bá jí Kristi dìde ninu òkú, a jẹ́ pé asán ni iwaasu wa, asán sì ni igbagbọ yín. Tí ó bá jẹ́ pé a kò jí àwọn òkú dìde, a tún jẹ́ pé a purọ́ mọ́ Ọlọrun, nítorí a jẹ́rìí pé ó jí Kristi dìde, bẹ́ẹ̀ sì ni kò jí i dìde. Nítorí pé bí a kò bá jí àwọn òkú dìde, a jẹ́ pé a kò jí Kristi dìde. Bí a kò bá sì jí Kristi dìde, a jẹ́ pé lásán ni igbagbọ yín, ẹ sì wà ninu ẹ̀ṣẹ̀ yín sibẹ. Tí ó bá wá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé àwọn onigbagbọ tí wọ́n ti kú ti ṣègbé! Tí ó bá jẹ́ pé ninu ayé yìí nìkan ni a ní ìrètí ninu Kristi, àwa ni ẹni tí àwọn eniyan ìbá máa káàánú jùlọ! Ṣugbọn òtítọ́ ọ̀rọ̀ yìí ni pé a ti jí Kristi dìde kúrò ninu òkú, òun sì ni àkọ́bí ninu àwọn tí wọ́n kú. Nítorí bí ó ti jẹ́ pé nípasẹ̀ eniyan ni ikú fi dé, nípasẹ̀ eniyan náà ni ajinde òkú fi dé. Nítorí bí ó ti jẹ́ pé nípasẹ̀ Adamu ni gbogbo eniyan ṣe kú, bẹ́ẹ̀ náà ni ó sì jẹ́ pé nípasẹ̀ Kristi ni a sọ gbogbo eniyan di alààyè. Ṣugbọn a óo jí olukuluku dìde létòlétò: Kristi ni ẹni àkọ́kọ́, lẹ́yìn náà, nígbà tí ó bá farahàn, a óo jí àwọn tíí ṣe tirẹ̀ dìde. Lẹ́yìn náà ni òpin yóo dé, lẹ́yìn tí ó bá ti dá ìjọba pada fún Ọlọrun Baba, tí ó sì ti pa gbogbo àṣẹ, ọlá ati agbára run. Nítorí ó níláti jọba títí Ọlọrun yóo fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá sí ìkáwọ́ rẹ̀. Ikú ni ọ̀tá ìkẹyìn tí yóo parun. Nítorí Ìwé Mímọ́ sọ pé, “Ó ti fi gbogbo nǹkan sí ìkáwọ́ rẹ̀.” Ṣugbọn nígbà tí ó sọ pé, “Gbogbo nǹkan ni ó fi sí ìkáwọ́ rẹ̀,” ó dájú pé ẹnìkan ni kò sí ní ìkáwọ́ rẹ̀: ẹni náà sì ni Ọlọrun tí ó fi gbogbo nǹkan sí ìkáwọ́ Kristi. Nígbà tí gbogbo nǹkan bá ti wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ tán, ni Ọmọ fúnrarẹ̀ yóo wá bọ́ sí ìkáwọ́ Ọlọrun tí ó fi gbogbo nǹkan sí ìkáwọ́ rẹ̀, kí Ọlọrun lè jẹ́ olórí ohun gbogbo ninu ohun gbogbo. Ó tún ku nǹkankan! Nítorí kí ni àwọn kan ṣe ń ṣe ìrìbọmi nítorí àwọn tí ó kú? Bí a kò bá ní jí àwọn òkú dìde, kí ni ìdí rẹ̀ tí wọ́n fi ń ṣe ìrìbọmi nítorí wọn? Àwa náà ńkọ́? Nítorí kí ni a ṣe ń fi ẹ̀mí wa wéwu nígbà gbogbo? Lojoojumọ ni mò ń kú! Ará, mo fi ìgbéraga tí mo ní ninu yín búra, àní èyí tí mo ní ninu Kristi Jesu Oluwa wa. Bí mo bá tìtorí iyì eniyan bá ẹranko jà ní Efesu, anfaani wo ni ó ṣe fún mi? Bí a kò bá jí àwọn òkú dìde, bí wọ́n ti máa ń wí, wọn á ní: “Ẹ jẹ́ kí á máa jẹ, kí á máa mu, nítorí ọ̀la ni a óo kú.” Ẹ má jẹ́ kí wọ́n tàn yín jẹ. Ẹgbẹ́ burúkú a máa ba ìwà rere jẹ́. Ẹ ronú, kí ẹ sì máa ṣe dáradára. Ẹ má dẹ́ṣẹ̀ mọ́. Àwọn tí kò mọ Ọlọrun wà láàrin yín! Mò ń sọ èyí kí ojú kí ó lè tì yín ni. Ṣugbọn ẹnìkan lè bèèrè pé, “Báwo ni a óo ti ṣe jí àwọn òkú dìde? Irú ara wo ni wọn óo ní?” Ìwọ òmùgọ̀ yìí! Bí irúgbìn tí a bá gbìn kò bá kọ́ kú, kò lè hù. Ohun tí ó bá hù kì í rí bí ohun tí a gbìn ti rí, nítorí pé irúgbìn lásán ni, ìbáà ṣe àgbàdo tabi àwọn ohun ọ̀gbìn yòókù. Ọlọrun ni ó ń fún un ní ara tí ó bá fẹ́, a fún irúgbìn kọ̀ọ̀kan ní ara tirẹ̀. Gbogbo ẹran-ara kì í ṣe oríṣìí kan náà. Ọ̀tọ̀ ni ẹran-ara eniyan, ọ̀tọ̀ ni ti ẹranko, ọ̀tọ̀ ni ti ẹyẹ, ọ̀tọ̀ ni ti ẹja. Àwọn nǹkan ẹlẹ́mìí tí ń fò lófuurufú wà. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ti orí ilẹ̀ wà. Ọ̀tọ̀ ni ẹwà ti àwọn tí ń fò lófuurufú. Ọ̀tọ̀ ni ẹwà àwọn ti orí ilẹ̀. Ọ̀tọ̀ ni ẹwà oòrùn, ọ̀tọ̀ ni ti òṣùpá, ọ̀tọ̀ ni ti àwọn ìràwọ̀, ìràwọ̀ ṣá yàtọ̀ sí ara wọn ní ẹwà. Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí nígbà ajinde àwọn òkú. A gbìn ín ní ara tíí díbàjẹ́; a jí i dìde ní ara tí kì í díbàjẹ́. A gbìn ín ní àìlọ́lá; a jí i dìde pẹlu ògo. A gbìn ín pẹlu àìlera: a jí i dìde pẹlu agbára. A gbìn ín pẹlu ara ti ẹ̀dá, a jí i dìde ní ara ti ẹ̀mí. Bí ara ti ẹ̀dá ti wà, bẹ́ẹ̀ ni ti ẹ̀mí wà. Ó wà ninu àkọsílẹ̀ pé, “Adamu, ọkunrin àkọ́kọ́ di alààyè;” ṣugbọn Adamu ìkẹyìn jẹ́ ẹ̀mí tí ó ń sọ eniyan di alààyè. Kì í ṣe ẹni ti ẹ̀mí ni ó kọ́kọ́ wà bíkòṣe ẹni ti ara, lẹ́yìn náà ni ẹni ti ẹ̀mí. Ọkunrin kinni tí a fi erùpẹ̀ dá jẹ́ erùpẹ̀, láti ọ̀run ni ọkunrin keji ti wá. Bí ẹni tí a fi erùpẹ̀ dá ti rí, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn tí a fi erùpẹ̀ dá rí. Bí ẹni tí ó wá láti ọ̀run ti rí, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ti ọ̀run rí. Bí a ti gbé àwòrán ti ẹni erùpẹ̀ wọ̀, bẹ́ẹ̀ gan-an ni a óo gbé àwòrán ti ẹni ọ̀run wọ̀. Ará, ohun tí mò ń sọ ni pé ẹran-ara ati ẹ̀jẹ̀ kò lè jogún ìjọba Ọlọrun, ati pé ohun tíí bàjẹ́ kò lè jogún ohun tí kì í bàjẹ́. Ẹ fetí sílẹ̀! Nǹkan àṣírí ni n óo sọ fun yín. Gbogbo wa kọ́ ni a óo kú, ṣugbọn nígbà tí fèrè ìkẹyìn bá dún, gbogbo wa ni a óo pa lára dà, kíá, bí ìgbà tí eniyan bá ṣẹ́jú. Nítorí fèrè yóo dún, a óo wá jí àwọn òkú dìde pẹlu ara tí kì í bàjẹ́, àwa náà yóo wá yipada. *** Nítorí ara tíí bàjẹ́ yìí níláti gbé ara tí kì í bàjẹ́ wọ̀; ara tí yóo kú yìí níláti gbé ara tí kì í kú wọ̀. Nígbà tí ara tíí bàjẹ́ bá ti gbé ara tí kì í bàjẹ́ wọ̀ tán, tí ara tí yóo kú bá sì ti gbé ara tí kì í kú wọ̀, nígbà náà ni ọ̀rọ̀ tí a ti kọ sílẹ̀ yóo wá ṣẹ pé, “A ti gbé ikú mì, a sì ti ṣẹgun.” “Ikú, oró rẹ dà? Isà òkú, ìṣẹ́gun rẹ dà?” Ẹ̀ṣẹ̀ ni ó fún ikú lóró. Òfin ni ó fún ẹ̀ṣẹ̀ lágbára. Ṣugbọn ọpẹ́ ni fún Ọlọrun tí ó fún wa ní ìṣẹ́gun nípasẹ̀ Oluwa wa Jesu Kristi. Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́, ẹ dúró gbọningbọnin, láì yẹsẹ̀. Ẹ tẹra mọ́ iṣẹ́ Oluwa nígbà gbogbo. Ẹ kúkú ti mọ̀ pé làálàá tí ẹ̀ ń ṣe níbi iṣẹ́ Oluwa kò ní jẹ́ lásán. Nípa ti ìtọrẹ tí ẹ̀ ń ṣe fún àwọn eniyan Ọlọrun, bí mo ti ṣe ètò pẹlu àwọn ìjọ Galatia, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe. Ní ọjọọjọ́ ìsinmi, kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín máa mú ọrẹ ninu ohun ìní rẹ̀, kí ó máa fi í sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun bá ti bukun un. Kí ó má ṣe jẹ́ pé nígbà tí mo bá dé ni ẹ óo ṣẹ̀ṣẹ̀ máa gba ọrẹ jọ. Nígbà tí mo bá dé, n óo kọ ìwé lé àwọn tí ẹ bá yàn lọ́wọ́, n óo rán wọn láti mú ọrẹ yín lọ sí Jerusalẹmu. Bí ó bá yẹ kí èmi náà lọ, wọn yóo bá mi lọ. Masedonia ni n óo kọ́ gbà kọjá, n óo wá wá sọ́dọ̀ yín. Bóyá n óo dúró lọ́dọ̀ yín, mo tilẹ̀ lè wà lọ́dọ̀ yín ní àkókò òtútù, kí ẹ lè sìn mí lọ sí ibi tí mo bá tún ń lọ. Nítorí pé, nígbà tí mo bá ń kọjá lọ, n kò fẹ́ kí ó jẹ́ pé mo kàn fi ojú bà yín lásán ni. Nítorí mo ní ìrètí pé n óo lè dúró lọ́dọ̀ yín fún ìgbà díẹ̀, bí Oluwa bá gbà bẹ́ẹ̀. Mo fẹ́ dúró ní Efesu níhìn-ín títí di àjọ̀dún Pẹntikọsti. Nítorí pé mo ní anfaani pupọ láti ṣiṣẹ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alátakò pọ̀. Bí Timoti bá dé, kí ẹ rí i pé ẹ fi í lára balẹ̀ láàrin yín, nítorí iṣẹ́ Oluwa tí mò ń ṣe ni òun náà ń ṣe. Kí ẹnikẹ́ni má ṣe fi àbùkù kàn án. Ẹ ṣe ètò ìrìn àjò fún un ní alaafia, kí ó lè wá sọ́dọ̀ mi, nítorí èmi ati àwọn arakunrin ń retí rẹ̀. Nípa ti arakunrin wa Apolo, mo gbà á níyànjú gidigidi pé kí ó wá sọ́dọ̀ yín pẹlu àwọn arakunrin yòókù. Ṣugbọn ó pinnu pé òun kò fẹ́ wá ní àkókò yìí. Ó ń bọ̀ nígbà tí ó bá yá. Ẹ máa ṣọ́nà. Ẹ dúró gbọningbọnin ninu igbagbọ. Ẹ ṣe bí ọkunrin. Ẹ jẹ́ alágbára. Ẹ máa ṣe gbogbo nǹkan tìfẹ́tìfẹ́. Ará, mo ní ẹ̀bẹ̀ kan láti fi siwaju yín. Ẹ mọ̀ pé ìdílé Stefana ni àwọn kinni tí ó kọ́kọ́ gbàgbọ́ ní ilẹ̀ Akaya; ati pé wọ́n ti yan ara wọn láti máa ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún àwọn eniyan Ọlọrun. Mo fẹ́ kí ẹ máa tẹ̀lé ọ̀rọ̀ irú wọn ati gbogbo àwọn tí wọn bá ń bá wọn ṣiṣẹ́ pọ̀, tí wọn ń ṣe làálàá níbi iṣẹ́ kan náà. Inú mi dùn nígbà tí Stefana ati Fotunatu ati Akaiku dé, nítorí dídé tí wọ́n dé dí àlàfo tí ó ṣí sílẹ̀ nítorí àìsí yín lọ́dọ̀ wa. Wọ́n mú kí ọkàn mi balẹ̀. Ati ti ẹ̀yin náà. Ẹ máa yẹ́ irú àwọn bẹ́ẹ̀ sí. Gbogbo ìjọ tí ó wà ní Esia kí yín. Akuila ati Pirisila ati ìjọ tí ó wà ní ilé wọn ki yín pupọ ninu Oluwa. Gbogbo àwọn onigbagbọ ki yín. Ẹ fi ìfẹnukonu alaafia kí ara yín. Ọwọ́ ara mi ni èmi Paulu fi kọ gbolohun ìkíni yìí. Bí ẹnikẹ́ni kò bá fẹ́ràn Oluwa wa, ẹni ègún ni! Marana ta –Oluwa wa, máa bọ̀! Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu kí ó wà pẹlu yín. Mo fi ìfẹ́ kí gbogbo yín ninu Kristi Jesu. Èmi Paulu, aposteli Kristi Jesu nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọlọrun, ati Timoti, arakunrin wa, ni à ń kọ ìwé yìí sí Ìjọ Ọlọrun tí ó wà ní Kọrinti ati sí gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun tí ó wà ní Akaya. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba wa ati Oluwa Jesu Kristi kí ó wà pẹlu yín. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, Baba Oluwa wa Jesu Kristi, Baba aláàánú ati Ọlọrun orísun ìtùnú, ẹni tí ó ń fún wa ní ìwúrí ninu gbogbo ìpọ́njú tí à ń rí, kí àwa náà lè fi ìwúrí fún àwọn tí ó wà ninu oríṣìíríṣìí ìpọ́njú nípa ìwúrí tí àwa fúnra wa ti níláti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Nítorí gẹ́gẹ́ bí a ti ní ìpín ninu ọpọlọpọ ìyà Kristi, bẹ́ẹ̀ náà ni a ní ọpọlọpọ ìwúrí nípasẹ̀ Kristi. Ṣugbọn bí a bá wà ninu ìpọ́njú, fún ìwúrí ati ìgbàlà yín ni. Bí a bá ní ìwúrí, ẹ̀yin náà yóo ní ìwúrí; ìwúrí yìí yóo sì kọ yín ní sùúrù nígbà tí ẹ bá ń jẹ irú ìyà tí àwa náà ń jẹ. Ìrètí wa lórí yín sì ti fẹsẹ̀ múlẹ̀, nítorí tí a mọ̀ pé bí a ti jọ ń jẹ irú ìyà kan náà, bẹ́ẹ̀ náà ni a jọ ní irú ìwúrí kan náà. Ẹ̀yin ará, a kò fẹ́ kí ẹ ṣe aláìmọ̀ nípa ìpọ́njú tí ó tayọ agbára wa tí a ní ní Esia, Ìdààmú náà wọ̀ wá lọ́rùn tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀mí wa fi fẹ́rẹ̀ bọ́. A ṣe bí wọ́n tí dá wa lẹ́bi ikú ni. Kí á má baà gbẹ́kẹ̀lé ara wa, bíkòṣe Ọlọrun, ni ọ̀rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀. Nítorí Ọlọrun níí jí òkú dìde. Ọlọrun ni ó yọ wá ninu ewu ńlá náà, òun ni yóo sì máa yọ wá. Òun ni a ní ìrètí ninu rẹ̀; yóo sì tún máa yọ wá, bí ẹ bá ń fi adura yín ràn wá lọ́wọ́. Nígbà náà ni ọpọlọpọ eniyan yóo ṣọpẹ́ nítorí ọpọlọpọ oore tí Ọlọrun ṣe fún wa. Nǹkankan wà tí a lè fi ṣe ìgbéraga, ẹ̀rí-ọkàn wa sì jẹ́rìí sí i pé pẹlu ọkàn kan ati inú kan níwájú Ọlọrun ni a fi ń bá gbogbo eniyan lò, pàápàá jùlọ ẹ̀yin gan-an. Kì í ṣe ọgbọ́n eniyan bíkòṣe oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun. Kò sí ohunkohun tí a kọ si yín tí ẹ kò lè kà kí ó ye yín. Mo sì ní ìrètí pé yóo ye yín jálẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ pé ẹ kò ì tíì mọ̀ wá dáradára, ẹ óo rí i pé a óo jẹ́ ohun ìṣògo fun yín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà yóo ti jẹ́ fún wa ní ọjọ́ tí Oluwa wa, Jesu, bá dé. Nítorí ó dá mi lójú bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe fẹ́ kọ́kọ́ wá sọ́dọ̀ yín, kí ayọ̀ yín lè di ìlọ́po meji. Ǹ bá gba ọ̀dọ̀ yín lọ sí Masedonia, ǹ bá sì tún gba ọ̀dọ̀ yín lábọ̀. Ǹ bá wá ṣe ètò láti wá ìrànlọ́wọ́ fún ìrìn àjò mi sí Judia. Ohun tí mo ní lọ́kàn nìyí. Ǹjẹ́ kò ní ìdí tí mo fi yí ètò yìí pada? Àbí ẹ rò pé nígbà tí mò ń ṣe ètò, mò ń ṣe é bí ẹni tí kò ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ni, tí ó fi jẹ́ pé ẹnu kan náà tí mo fi pe “bẹ́ẹ̀ ni” ni n óo tún fi pe “bẹ́ẹ̀ kọ́?” Gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, ọ̀rọ̀ wa pẹlu yín ti kúrò ní “bẹ́ẹ̀ ni” ati “bẹ́ẹ̀ kọ́.” Nítorí Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọrun, tí èmi, Silifanu ati Timoti, ń waasu rẹ̀ fun yín, kì í ṣe “bẹ́ẹ̀ ni” ati “bẹ́ẹ̀ kọ́”. Ṣugbọn “bẹ́ẹ̀ ni” ni tirẹ̀. Nítorí gbogbo ìlérí Ọlọrun di “bẹ́ẹ̀ ni” ninu rẹ̀. Ìdí tí a fi ń ṣe “Amin” ní orúkọ rẹ̀ nìyí, nígbà tí a bá ń fi ògo fún Ọlọrun. Ọlọrun ni ó fún àwa ati ẹ̀yin ní ìdánilójú pé a wà ninu Kristi, òun ni ó ti fi òróró yàn wá. Ó ti fi èdìdì rẹ̀ sí wa lára, ó tún fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe onídùúró sí ọkàn wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ohun tí yóo tún fún wa. Mo fi Ọlọrun jẹ́rìí ohun tí n óo sọ yìí. Mo sì fi ẹ̀mí mi búra! Ìdí tí n kò fi wá sí Kọrinti mọ́ ni pé n kò fẹ́ yọ yín lẹ́nu. Kì í ṣe pé a ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ fi agbára ti igbagbọ bọ̀ yín lọ́rùn ni, nítorí ẹ ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ ninu igbagbọ. Ṣugbọn a jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹlu yín ni, kí ẹ lè ní ayọ̀. Nítorí náà, mo pinnu pé n kò tún fẹ́ kí wíwá tí mo bá wá sọ́dọ̀ yín jẹ́ ti ìbànújẹ́ mọ́. Bí mo bá bà yín ninu jẹ́, ta ni yóo mú inú mi dùn bí kò bá ṣe ẹ̀yin kan náà tí mo bà ninu jẹ́? Ìdí tí mo fi kọ ìwé tí mo kọ si yín nìyí, nítorí n kò fẹ́ wá kí n tún ní ìbànújẹ́ láti ọ̀dọ̀ ẹ̀yin tí ó yẹ kí ẹ fún mi láyọ̀. Ó dá mi lójú pé bí mo bá ń yọ̀, inú gbogbo yín ni yóo máa dùn. Nítorí pẹlu ọpọlọpọ ìdààmú ati ọkàn wúwo ni mo fi kọ ọ́, kì í ṣe pé kí ó lè bà yín lọ́kàn jẹ́ ṣugbọn kí ẹ lè mọ̀ pé ìfẹ́ tí mo ní si yín pọ̀ pupọ. Ní ti ẹni tí ó dá ìbànújẹ́ yìí sílẹ̀, èmi kọ́ ni ó bà ninu jẹ́ rárá. Láì tan ọ̀rọ̀ náà lọ títí, bí ó ti wù kí ó mọ, gbogbo yín ni ó bà ninu jẹ́. Ìyà tí ọpọlọpọ ninu yín ti fi jẹ irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti tó. Kí ẹ wá dáríjì í. Kí ẹ fún un ní ìwúrí. Bí ìbànújẹ́ bá tún pọ̀ lápọ̀jù kí ó má baà wó irú ẹni bẹ́ẹ̀ mọ́lẹ̀. Mo bẹ̀ yín pé kí ẹ jẹ́ kí ó mọ̀ pé ẹ fẹ́ràn òun. Ìdí tí mo fi kọ ìwé sí yín ni láti fi dán yín wò, kí n lè mọ̀ bí ẹ bá ń gbọ́ràn sí mi lẹ́nu ninu ohun gbogbo. Bí ẹ bá dáríjì ẹnikẹ́ni, èmi náà dáríjì í. Nítorí tí mo bá ti dáríjì eniyan, (bí nǹkankan bá fi ìgbà kan wà tí mo fi níláti dáríjì ẹnikẹ́ni), mo ṣe é nítorí tiyín níwájú Kristi. Nítorí a kò gbọdọ̀ gba Èṣù láyè láti lò wá, nítorí a kò ṣàì mọ ète rẹ̀. Nígbà tí mo dé Tiroasi láti waasu ìyìn rere Kristi, Oluwa ṣínà fún mi láti ṣiṣẹ́. Ṣugbọn ọkàn mi kò balẹ̀ nígbà tí n kò rí Titu arakunrin mi níbẹ̀. Mo bá dágbére fún àwọn eniyan níbẹ̀, mo lọ sí Masedonia. Ṣugbọn ọpẹ́ ni fún Ọlọrun tí ó jẹ́ kí á lè wà ninu àjọyọ̀ ìṣẹ́gun tí Kristi ṣẹgun, nígbà gbogbo. Ọlọrun náà ni ó tún ń mú kí ìmọ̀ rẹ̀ tí ń jáde láti ara wa máa gba gbogbo ilẹ̀ káàkiri bí òórùn dídùn níbi gbogbo. Nítorí àwa ni òórùn dídùn tí Kristi fi rúbọ sí Ọlọrun lọ́dọ̀ àwọn tí à ń gbàlà ati àwọn tí ń ṣègbé. Fún àwọn tí wọn ń ṣègbé, a dàbí òórùn tí n pani, ṣugbọn fún àwọn tí à ń gbàlà, a dàbí òórùn dídùn tí ó ń fún wọn ní ìyè. Ta ló tó ṣe irú iṣẹ́ yìí? Nítorí àwa kì í ṣe àwọn tí ń ba ọ̀rọ̀ Ọlọrun jẹ́ nítorí èrè tí wọn óo rí jẹ níbẹ̀, bí ọpọlọpọ tí ń ṣe. Ṣugbọn à ń waasu pẹlu ọkàn kan bí eniyan Kristi, ati gẹ́gẹ́ bí ẹni tí Ọlọrun rán níṣẹ́, tí ó ń ṣiṣẹ́ níwájú Ọlọrun. Ṣé a óo ṣẹ̀ṣẹ̀ tún bẹ̀rẹ̀ láti máa ṣe àpèjúwe ara wa ni; àbí a nílò láti mú ìwé ẹ̀rí tọ̀ yín wá tí yóo sọ irú ẹni tí a jẹ́ fun yín, tabi kí á gbà lọ láti ọ̀dọ̀ yín? Ẹ̀yin alára ni ìwé wa, tí a ti kọ sí ọkàn wa. Gbogbo eniyan ni wọ́n mọ ìwé yìí, tí wọ́n sì ń kà á. Ó hàn gbangba pé ẹ̀yin ni ìwé tí Kristi kọ, tí ó fi rán wa. Kì í ṣe irú èyí tí wọ́n fi yíǹkì kọ, Ẹ̀mí Ọlọrun alààyè ni wọ́n fi kọ ọ́. Kì í ṣe èyí tí wọ́n kọ sí orí òkúta; ọkàn eniyan ni wọ́n kọ ọ́ sí. A lè sọ èyí nítorí a ní igbẹkẹle ninu Ọlọrun nípa Kristi. Kì í ṣe pé a ní agbára tó ninu ara wa, tabi pé a ti lè ṣe nǹkankan fúnra wa. Ṣugbọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni a ti ní gbogbo nǹkan ní ànító. Ọlọrun ni ó mú kí á lè jẹ́ iranṣẹ ti majẹmu titun, tí kì í ṣe ti òfin tí a kọ bíkòṣe ti Ẹ̀mí. Nítorí ikú ni òfin tí a kọ sílẹ̀ ń mú wá, ṣugbọn majẹmu ti Ẹ̀mí ń sọ eniyan di alààyè. Bí òfin tí a kọ sí ara òkúta tí ó jẹ́ iranṣẹ ikú bá wá pẹlu ògo, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli kò lè ṣíjú wo Mose, nítorí ìmọ́lẹ̀ tí ń tàn ní ojú rẹ̀ fún àkókò díẹ̀, báwo ni iranṣẹ ti Ẹ̀mí yóo ti lógo tó? Bí iṣẹ́ tí à ń torí rẹ̀ dá wa lẹ́bi bá lógo, báwo ni iṣẹ́ tí à ń torí rẹ̀ dá wa láre yóo ti lógo tó? Àní ohun tí ó lógo tẹ́lẹ̀ kò tún lógo mọ́ nítorí ohun mìíràn tí ògo tirẹ̀ ta á yọ. Nítorí bí ohun tí yóo pada di asán bá lógo, mélòó-mélòó ni ti ohun tí yóo wà títí laelae? Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí a ní irú ìrètí yìí, a ń fi ìgboyà pupọ sọ̀rọ̀. A kò dàbí Mose tí ó fi aṣọ bojú rẹ̀, kí àwọn ọmọ Israẹli má baà rí ògo ojú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni ògo tíí ṣá ni. Ṣugbọn ọkàn wọn ti le, nítorí títí di ọjọ́ òní, aṣọ náà ni ó ń bo ọkàn wọn nígbà tí wọn bá ń ka ìwé majẹmu àtijọ́. Wọn kò mú aṣọ náà kúrò, nítorí nípasẹ̀ Kristi ni majẹmu àtijọ́ fi di asán. Ṣugbọn títí di ọjọ́ òní, nígbàkúùgbà tí wọn bá ń ka Òfin Mose, aṣọ a máa bo ọkàn wọn. Gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti sọ nípa Mose, “Nígbàkúùgbà tí ó bá yipada sí Oluwa, a mú aṣọ kúrò lójú.” Ǹjẹ́ Oluwa tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ni Ẹ̀mí Mímọ́. Níbikíbi tí Ẹ̀mí Oluwa bá wà, òmìnira wà níbẹ̀. Kò sí aṣọ tí ó bò wá lójú. Ojú gbogbo wa ń fi ògo Oluwa hàn bí ìgbà tí eniyan ń wo ojú rẹ̀ ninu dígí. À ń pa wá dà sí ògo mìíràn tí ó tayọ ti àkọ́kọ́. Èyí jẹ́ iṣẹ́ Oluwa tí í ṣe Ẹ̀mí. Nítorí èyí, níwọ̀n ìgbà tí ó wu Ọlọrun ninu àánú rẹ̀ láti fi iṣẹ́ yìí fún wa ṣe, ọkàn wa kò rẹ̀wẹ̀sì. A ti kọ àwọn ohun ìkọ̀kọ̀ tíí máa ti eniyan lójú sílẹ̀. A kò hùwà ẹ̀tàn, bẹ́ẹ̀ ni a kò yí ọ̀rọ̀ Ọlọrun po. Ṣugbọn ọ̀nà tí a fi gba iyì ninu ẹ̀rí-ọkàn eniyan ati níwájú Ọlọrun ni pé à ń fi òtítọ́ hàn kedere. Ṣugbọn tí ìyìn rere wa bá ṣókùnkùn, àwọn tí yóo ṣègbé ni ó ṣókùnkùn sí. Àwọn oriṣa ayé yìí ni wọ́n fọ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lójú, tí ọkàn wọn kò fi lè gbàgbọ́. Èyí ni kò jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ ìyìn rere Kristi, tí ó lógo, kí ó tàn sí wọn lára; àní, Kristi tíí ṣe àwòrán Ọlọrun. Nítorí kì í ṣe nípa ara wa ni à ń waasu. Ẹni tí à ń waasu rẹ̀ ni Jesu Kristi pé òun ni Oluwa. Iranṣẹ yín ni a jẹ́, nítorí ti Kristi. Nítorí Ọlọrun tí ó ní kí ìmọ́lẹ̀ tàn láti inú òkùnkùn, òun ni ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ọkàn wa, kí ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ ògo Ọlọrun lè tàn sí wa ní ojú Kristi. Ṣugbọn bí ìkòkò amọ̀ ni àwa tí ìṣúra yìí wà ninu wa rí, kí ó lè hàn gbangba pé Ọlọrun ni ó ní agbára tí ó tóbi jùlọ, kì í ṣe àwa. A ní oríṣìíríṣìí ìṣòro, ṣugbọn wọn kò wó wa mọ́lẹ̀; ọkàn wa ń dààmú, ṣugbọn a kò ṣe aláìní ìrètí. Àwọn eniyan ń ṣe inúnibíni sí wa, ṣugbọn Ọlọrun kò fi wá sílẹ̀. Wọ́n gbé wa ṣubú, ṣugbọn wọn kò lè pa wá. À ń ru ikú Jesu káàkiri lára wa nígbà gbogbo, kí ìyè Jesu lè hàn lára wa. Nítorí pé nígbà gbogbo ni à ń fi ẹ̀mí wa wéwu nítorí Jesu, níwọ̀n ìgbà tí a wà láàyè, kí ìyè Jesu lè hàn ninu ẹran-ara wa tí yóo di òkú. Ó wá jẹ́ pé ikú ní ń ṣiṣẹ́ ninu wa, nígbà tí ìyè ń ṣiṣẹ́ ninu yín. Àkọsílẹ̀ kan sọ pé, “Mo gbàgbọ́, nítorí náà ni mo fi sọ̀rọ̀.” Nígbà tí ó ti jẹ́ pé a ní ẹ̀mí igbagbọ kan náà, àwa náà gbàgbọ́, nítorí náà ni a fi ń sọ̀rọ̀. A mọ̀ pé ẹni tí ó jí Oluwa Jesu dìde yóo jí àwa náà dìde pẹlu Jesu, yóo wá mú àwa ati ẹ̀yin wá sí iwájú rẹ̀. Nítorí tiyín ni gbogbo èyí, kí oore-ọ̀fẹ́ lè máa pọ̀ sí i fún ọpọlọpọ eniyan, kí ọpẹ́ yín lè máa pọ̀ sí i fún ògo Ọlọrun. Nítorí náà ni a kò fi sọ ìrètí nù. Nítorí pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ara wa ti òde ń bàjẹ́, ṣugbọn ara wa ti inú ń di titun sí i lojoojumọ. Ìjìyà wa mọ níwọ̀n, ati pé fún àkókò díẹ̀ ni. Àyọrísí rẹ̀ ni ògo tí ó pọ̀ pupọ, tí yóo wà títí, tí ó sì pọ̀ ju ìyà tí à ń jẹ lọ. Kì í ṣe àwọn nǹkan tí a lè fi ojú rí ni a tẹjúmọ́, bíkòṣe àwọn nǹkan tí a kò lè fi ojú rí. Nítorí àwọn nǹkan tí yóo wà fún ìgbà díẹ̀ ni àwọn nǹkan tí a lè fi ojú rí. Àwọn nǹkan tí a kò lè fi ojú rí ni yóo wà títí laelae. Nítorí a mọ̀ pé bí àgọ́ ara tí a fi ṣe ilé ní ayé yìí bá wó, a ní ilé kan lọ́dọ̀ Ọlọrun, tí a kò fi ọwọ́ kọ́, tí yóo wà lọ́run títí laelae. Nítorí ninu àgọ́ ara yìí à ń kérora, à ń tiraka láti gbé ilé wa ti ọ̀run wọ̀. A ní ìrètí pé bí a bá gbé e wọ̀, a kò ní bá ara wa níhòòhò. Àwa tí a wà ninu àgọ́ ara yìí ń kérora nítorí pé ara ń ni wá, kò jẹ́ pé a fẹ́ bọ́ àgọ́ ara yìí sílẹ̀, ṣugbọn àgọ́ ara yìí ni a fẹ́ gbé ara titun wọ̀ lé, kí ara ìyè lè gbé ara ikú mì. Ẹni tí ó ṣe iṣẹ́ yìí lára wa ni Ọlọrun. Ó sì fún wa ní Ẹ̀mí Mímọ́, ó fi ṣe onídùúró gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ohun tí yóo tún fún wa. Nítorí náà, a ní ìgboyà nígbà gbogbo. A mọ̀ pé níwọ̀n ìgbà tí a bá fi ara yìí ṣe ilé, a dàbí ẹni tí ó jáde kúrò lọ́dọ̀ Oluwa. Nítorí igbagbọ ni a fi ń gbé ìgbé-ayé wa, kì í ṣe ohun tí à ń fi ojú rí. Bí mo ti sọ, a ní ìgboyà. Inú wa ìbá sì dùn kí á kúrò ninu àgọ́ ti ara yìí, kí á bọ́ sinu ilé lọ́dọ̀ Oluwa. Nítorí èyí, kì báà jẹ́ pé a wà ninu ilé ti ibí, tabi kí á bọ́ sinu ilé ti ọ̀hún, àníyàn wa ni pé kí á sá jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Oluwa. Nítorí gbogbo wa níláti lọ siwaju Kristi bí a ti rí, láti lọ jẹ́ ẹjọ́. Níbẹ̀ ni olukuluku yóo ti gba ohun tí ó tọ́ sí i fún oríṣìíríṣìí ìwà tí ó ti hù nígbà tí ó wà ninu ara, ìbáà ṣe rere, ìbáà ṣe burúkú. Nítorí náà nígbà tí àwa ti mọ ohun tí ìbẹ̀rù Oluwa jẹ́, a mọ̀ pé eniyan ni a lè gbìyànjú láti yí lọ́kàn pada. Ọlọrun mọ irú ẹni tí a jẹ́, mo sì rò pé ẹ̀rí-ọkàn yín jẹ́rìí sí mi pẹlu. Kò tún nílò pé kí á máa pọ́n ara wa fun yín mọ́. Ṣugbọn èyí yóo jẹ́ anfaani fun yín láti máa fi wá ṣògo, kí ẹ lè máa rí ohun wí fún àwọn tí wọn ń ṣògo nípa nǹkan ti òde ara, tí kì í ṣe nípa nǹkan ti inú ọkàn. Bí ó bá dàbí ẹni pé orí wa kò pé, nítorí ti Ọlọrun ni. Bí a bá jẹ́ ọlọ́gbọ́n, a jẹ́ ẹ fun yín, nítorí ìfẹ́ Kristi ni ó ń darí wa, nígbà tí a ti mọ̀ pé ẹnìkan ti kú fún gbogbo eniyan, a mọ̀ pé ikú gbogbo eniyan ni ó gbà kú. Ìdí tí Kristi fi kú fún gbogbo eniyan ni pé kí àwọn tí ó wà láàyè má ṣe wà láàyè fún ara wọn, ṣugbọn kí wọ́n lè wà láàyè fún ẹni tí ó kú fún wa, tí Ọlọrun sì jí dìde. Àyọrísí gbogbo èyí ni pé, láti ìgbà yìí lọ, àwa kò tún ní wo ẹnikẹ́ni ní ìwò ti ẹ̀dá mọ́. Nígbà kan ìwò ti ẹ̀dá ni à ń wo Kristi, ṣugbọn a kò tún wò ó bẹ́ẹ̀ mọ́. Èyí ni pé nígbà tí ẹnikẹ́ni bá wà ninu Kristi, ó di ẹ̀dá titun. Ohun àtijọ́ ti kọjá lọ. Ìgbé-ayé irú ẹni bẹ́ẹ̀ sì di titun. Iṣẹ́ Ọlọrun ni èyí láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. Òun ni ó ti là wá níjà pẹlu ara rẹ̀ nípasẹ̀ Kristi. Òun kan náà ni ó tún fún wa ní iṣẹ́ ìlàjà ṣe. Iṣẹ́ náà ni pé Ọlọrun wà ninu Kristi, ó ń làjà láàrin aráyé ati ara rẹ̀. Kò ka àwọn ìwà àìṣedéédé wọn sí wọn lọ́rùn. Ó sì ti wá fi ọ̀rọ̀ ìlàjà lé wa lọ́wọ́. Nítorí náà, a jẹ́ aṣojú fún Kristi. Ó dàbí ẹni pé àwa ni Ọlọrun ń lò láti fi bẹ̀ yín. A fi orúkọ Kristi bẹ̀ yín, ẹ bá Ọlọrun rẹ́. Kristi kò dẹ́ṣẹ̀. Sibẹ nítorí tiwa, Ọlọrun sọ ọ́ di ọ̀kan pẹlu ẹ̀dá ẹlẹ́ṣẹ̀, kí á lè di olódodo níwájú Ọlọrun nípa rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí alábàáṣiṣẹ́pọ̀, à ń bẹ̀ yín pé kí ẹ má ṣe jẹ́ kí gbígbà tí ẹ gba oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun jẹ́ lásán. Nítorí Ọlọrun sọ pé, “Mo gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ nígbà tí o bá ojurere mi pàdé; mo ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ọjọ́ ìgbàlà.” Ìsinsìnyìí ni àkókò ojurere Ọlọrun. Òní ni ọjọ́ ìgbàlà. A kò fi ohun ìkọsẹ̀ kankan siwaju ẹnikẹ́ni, kí àwọn eniyan má baà rí wí sí iṣẹ́ wa. Ṣugbọn ninu gbogbo nǹkan, à ń fi ara wa sípò àyẹ́sí gẹ́gẹ́ bí iranṣẹ Ọlọrun. A ti fara da ọpọlọpọ nǹkan ní àkókò inúnibíni, ninu ìdààmú, ati ninu ìṣòro; nígbà tí wọ́n nà wá ati nígbà tí a wà lẹ́wọ̀n, ní àkókò ìrúkèrúdò ati ní àkókò tí iṣẹ́ wọ̀ wá lọ́rùn, tí à ń pa ebi mọ́nú. À ń ṣiṣẹ́ pẹlu ọkàn kan; pẹlu ọgbọ́n ati sùúrù, pẹlu inú rere ati ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, pẹlu ìfẹ́ tí kò lẹ́tàn. À ń ṣe iṣẹ́ wa pẹlu òtítọ́ inú ati agbára Ọlọrun. A mú ohun ìjà òdodo lọ́wọ́ ọ̀tún ati lọ́wọ́ òsì. Bí a ti ń gba ọlá, bẹ́ẹ̀ ni à ń gba ìtìjú. Bí a ti ń gba èébú, bẹ́ẹ̀ ni à ń gba ìyìn. Àwọn ẹlòmíràn kà wá sí ẹlẹ́tàn, bẹ́ẹ̀ sì ni olóòótọ́ ni wá. Ìwà wa kò yé àwọn eniyan, sibẹ gbogbo eniyan ni ó mọ̀ wá. A dàbí ẹni tí ń kú lọ, sibẹ a tún wà láàyè. A ti ní ìrírí ìtọ́ni pẹlu ìjìyà, sibẹ ìjìyà yìí kò pa wá. A ní ìrírí ìbànújẹ́ nígbà gbogbo, sibẹ à ń yọ̀. A jẹ́ aláìní, sibẹ a ti sọ ọpọlọpọ di ọlọ́rọ̀. A dàbí àwọn tí kò ní nǹkankan, sibẹ a ní ohun gbogbo. A ti sọ òtítọ́ inú wa fun yín, ẹ̀yin ará Kọrinti. Ọkàn wa ṣípayá si yín. Kò sí ohun kan ní ọkàn wa si yín. Bí ohun kan bá wà, a jẹ́ pé ní ọkàn tiyín ni. Mò ń ba yín sọ̀rọ̀ bí ọmọ. Ohun tí ó yẹ yín ni pé kí ẹ ṣí ọkàn yín payá sí wa. Ẹ má ṣe da ara yín pọ̀ mọ́ àwọn alaigbagbọ. Nítorí ìrẹ́pọ̀ wo ni ó wà láàrin ìwà òdodo ati aiṣododo? Tabi, kí ni ó pa ìmọ́lẹ̀ ati òkùnkùn pọ̀? Báwo ni Kristi ti ṣe lè fi ohùn ṣọ̀kan pẹlu Èṣù? Kí ni ìbá pa onigbagbọ ati alaigbagbọ pọ̀? Kí ni oriṣa ń wá ninu ilé Ọlọrun? Nítorí ilé Ọlọrun alààyè ni àwa jẹ́. Gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti sọ, pé, “N óo máa gbé ààrin wọn, n óo máa káàkiri ní ààrin wọn. N óo jẹ́ Ọlọrun wọn, wọn yóo sì jẹ́ eniyan mi. Nítorí náà ẹ jáde kúrò láàrin wọn, ẹ ya ara yín sọ́tọ̀, ni Oluwa wí. Ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́, kí n lè gbà yín. N óo jẹ́ baba fun yín, ẹ̀yin náà óo sì jẹ́ ọmọ fún mi, lọkunrin ati lobinrin yín. Èmi Oluwa Olodumare ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” Nítorí náà, ẹ̀yin àyànfẹ́, nígbà tí ẹ ti ní àwọn ìlérí yìí, ẹ wẹ gbogbo ìdọ̀tí kúrò ní ara ati ẹ̀mí yín. Ẹ ya ara yín sí mímọ́ patapata pẹlu ìbẹ̀rù Ọlọrun. Ẹ fi wá sọ́kàn. A kò ṣẹ ẹnikẹ́ni. A kò ba ẹnikẹ́ni jẹ́. A kò sì rẹ́ ẹnikẹ́ni jẹ. Kì í ṣe pé mò ń fi èyí ba yín wí. Nítorí, bí mo ti sọ ṣáájú, ẹ ṣe ọ̀wọ́n fún wa tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé bí ó bá kan ti ikú, kí á jọ kú ni, bí ó bá sì jẹ́ ti ìyè, kí á jọ wà láàyè ni. Ọkàn mi balẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yín. Mò ń fi ọwọ́ yín sọ̀yà. Mò ti ní ìtùnú kíkún. Ninu gbogbo ìpọ́njú wa, mo ní ayọ̀ lọpọlọpọ. Nígbà tí a dé Masedonia, ọkàn wa kò balẹ̀ rárá. Wahala ni lọ́tùn-ún lósì, ìjà lóde, ẹ̀rù ninu. Ṣugbọn Ọlọrun tí ń tu àwọn tí ọkàn wọn bá rẹ̀wẹ̀sì ninu, ti tù wá ninu nígbà tí Titu dé. Kì í sìí ṣe ti dídé tí ó dé nìkan ni, ṣugbọn ó ròyìn fún wa, gbogbo bí ẹ ti dá a lọ́kàn le ati gbogbo akitiyan yín lórí wa, bí ọkàn yín ti bàjẹ́ tó fún ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ati bí ẹ ti ní ìtara tó fún mi. Èyí mú kí inú mi dùn pupọ. Bí ó bá jẹ́ pé ìwé tí mo kọ bà yín ninu jẹ́, n kò kábàámọ̀ rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti kọ́ kábàámọ̀ pé ìwé náà bà yín lọ́kàn jẹ́ fún ìgbà díẹ̀, ṣugbọn nisinsinyii mo láyọ̀. Kì í ṣe nítorí pé ó bà yín lọ́kàn jẹ́, ṣugbọn nítorí pé bíbà tí ó bà yín lọ́kàn jẹ́ ni ó jẹ́ kí ẹ ronupiwada. Nítorí ẹ farada ìbànújẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti fẹ́, kí ẹ má baà pàdánù nítorí ohun tí a ṣe. Ìbànújẹ́ tí eniyan bà faradà gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti fẹ́ a máa mú kí eniyan ronupiwada kí ó sì rí ìgbàlà, tí kò ní àbámọ̀ ninu. Ṣugbọn tí eniyan bá kàn ní ìbànújẹ́ lásán, ikú ni àyọrísí rẹ̀. Ṣé ẹ wá rí i bí ìbànújẹ́ tí ẹ faradà gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti fẹ́, ti yọrí sí fun yín? Ó mú kí ẹ fi ìtara mú ọ̀rọ̀ náà, kí ẹ sì jà fún ara yín. Ó mú kí inú bi yín sí ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Ó mú ìbẹ̀rù wá sọ́kàn yín. Ó mú kí ẹ ṣe aájò mi. Ó mú kí ẹ ní ìtara. Ó mú kí ẹ rí i pé ẹ ṣe ẹ̀tọ́ ninu ọ̀ràn náà. Ní gbogbo ọ̀nà ẹ ti fihàn pé ọwọ́ yín mọ́ ninu ọ̀ràn náà. Nígbà tí mo kọ ìwé tí mo kọ́ kọ, kì í ṣe nítorí ti ẹni tí ó ṣe àìdára, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nítorí ti ẹni tí wọ́n ṣe àìdára sí. Ṣugbọn mo kọ ọ́ kí ìtara yín lè túbọ̀ hàn níwájú Ọlọrun. Ìdí rẹ̀ nìyí tí a fi ní ìtùnú. Lẹ́yìn pé a ní ìtùnú, a tún ní ayọ̀ pupọ nígbà tí a rí bí ayọ̀ Titu ti pọ̀ tó, nítorí ọkàn rẹ̀ balẹ̀ láàrin gbogbo yín. Nítorí bí mo bá ti sọ ohunkohun nípa yín, tí mo sì ti fi ọwọ́ yín sọ̀yà, ẹ kò dójú tì mí. Ṣugbọn bí ó ti jẹ́ pé òtítọ́ ni gbogbo nǹkan tí a ti sọ fun yín, bẹ́ẹ̀ náà ni ọwọ́ yín tí a fi sọ̀yà fún Titu jẹ́ òtítọ́. Inú Titu dùn si yín lọpọlọpọ nígbà tí ó ranti bí gbogbo yín ti múra láti ṣe ohun tí ó sọ fun yín ati bí ẹ ti gbà á pẹlu ìbẹ̀rù ati ìwárìrì. Mo láyọ̀ pé mo lè gbẹ́kẹ̀lé yín ninu ohun gbogbo. Ẹ̀yin ará, a fẹ́ kí ẹ mọ ohun tí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun ti ṣe láàrin àwọn ìjọ Masedonia. Wọ́n ní ọpọlọpọ ìdánwò nípa ìpọ́njú. Sibẹ wọ́n ní ayọ̀ pupọ. Wọ́n ṣe aláìní pupọ, sibẹ wọ́n lawọ́ gan-an. Nítorí mo jẹ́rìí pé wọ́n sa ipá wọn, wọ́n tilẹ̀ ṣe tayọ agbára wọn, tìfẹ́tìfẹ́ ni wọ́n sì fi ṣe é. Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ìwúrí ni wọ́n fi bẹ̀ wá pé kí á jẹ́ kí àwọn náà lọ́wọ́ ninu iṣẹ́ oore-ọ̀fẹ́ yìí fún àwọn onigbagbọ. Wọ́n tilẹ̀ ṣe ju bí a ti lérò lọ, nítorí pé ara wọn pàápàá ni wọ́n kọ́ gbé bùn wá, tí wọ́n sì yọ̀ǹda fún Ọlọrun nípa ìfẹ́ rẹ̀. Ìdí nìyí tí a fi gba Titu níyànjú pé, nígbà tí ó jẹ́ pé òun ni ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ oore-ọ̀fẹ́ yìí láàrin yín, kí ó kúkú ṣe é parí. Gbogbo nǹkan wọnyi ni ẹ ní, tí ẹ sì ní lọpọlọpọ: igbagbọ, ọ̀rọ̀ sísọ, ìmọ̀, ati ìtara ní ọ̀nà gbogbo, bẹ́ẹ̀ náà ni ìfẹ́ tí ẹ ní sí wa. A fẹ́ kí ìtara yín túbọ̀ pọ̀ sí i nípa ṣíṣe iṣẹ́ ìfẹ́ pẹlu. N kò pa èyí láṣẹ. Mo fi àpẹẹrẹ ìtara àwọn ẹlòmíràn siwaju yín láti fi dán yín wò ni, bóyá ẹ ní ìfẹ́ tòótọ́ tabi ẹ kò ní. Nítorí ẹ mọ oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu Kristi, pé nítorí tiwa, òun tí ó jẹ́ ọlọ́rọ̀ di aláìní, kí ẹ lè di ọlọ́rọ̀ nípa àìní tirẹ̀. Èrò mi lórí ọ̀rọ̀ yìí ni pé ohun tí ó dára jùlọ fun yín ni. Nígbà tí kì í tíí ṣe pé ẹ ti ń ṣe é nìkan ni, ṣugbọn tìfẹ́tìfẹ́ ni ẹ ti fi ń ṣe é láti ọdún tí ó kọjá, ó tó àkókò wàyí, ẹ ṣe é parí. Irú ìtara tí ẹ fẹ́ fi ṣe é ni kí ẹ fi parí rẹ̀. Kí ẹ ṣe é gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ní tó. Bí ìfẹ́ láti mú ọrẹ wá bá wà, Ọlọrun gba ohun tí eniyan bá mú wá. Ọlọrun kò bèèrè ohun tí eniyan kò ní. Kì í ṣe pé, kí àwọn ẹlòmíràn má ṣe nǹkankan, kí ó jẹ́ pé ẹ̀yin nìkan ni ọrùn yóo wọ̀. Ṣugbọn ọ̀ràn kí ẹ jọ pín in ṣe ní dọ́gba-dọ́gba ni. Ní àkókò yìí, ọ̀pọ̀ tí ẹ ní yóo mú kí ẹ lè pèsè fún àìní àwọn tí ẹ̀ ń rànlọ́wọ́. Ní ọjọ́ iwájú, ọ̀pọ̀ tí àwọn náà bá ní yóo mú kí wọ́n lè pèsè fún àìní yín. Ọ̀rọ̀ ojuṣaaju kò ní sí níbẹ̀. *** Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀, “Ẹni tí ó kó ọ̀pọ̀ kò ní jù, ẹni tí ó kó díẹ̀ kò ṣe aláìní tó.” Ọpẹ́ ni fún Ọlọrun tí ó fi irú ìtara kan náà tí mo ní sí ọkàn Titu. Nítorí nígbà tí a sọ pé kí ó wá sọ́dọ̀ yín, pẹlu ayọ̀ ni ó fi gbà láti wá. Òun fúnrarẹ̀ tilẹ̀ ní àníyàn láti wá sọ́dọ̀ yín tẹ́lẹ̀. A rán arakunrin tí ó lókìkí ninu gbogbo àwọn ìjọ nítorí iṣẹ́ rẹ̀ nípa ìyìn rere pé kí ó bá a wá. Kì í ṣe pé ó lókìkí nìkan ni, ṣugbọn òun ni ẹni tí gbogbo àwọn ìjọ yàn pé kí ó máa bá wa kiri nípa iṣẹ́ oore-ọ̀fẹ́ tí à ń ṣe fún ògo Oluwa ati láti fi ìtara wa hàn. À ń ṣe èyí kí ẹnikẹ́ni má baà rí nǹkan wí sí wa nípa ọ̀nà tí à ń gbà ṣe ètò ti ẹ̀bùn yìí. Nítorí ète wa dára lójú Oluwa, ó sì dára lójú àwọn eniyan pẹlu. A tún rán arakunrin wa tí a ti dánwò ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà ní ti ìtara rẹ̀ pé kí ó bá wọn wá. Nisinsinyii ó túbọ̀ ní ìtara pupọ nítorí ó gbẹ́kẹ̀lé yín pupọ. Ní ti Titu, ẹlẹgbẹ́ mi ati alábàáṣiṣẹ́ mi ni ninu ohun tí ó kàn yín. Ní ti àwọn arakunrin wa, òjíṣẹ́ àwọn ìjọ ni wọ́n, Ògo Kristi sì ni wọ́n. Nítorí náà ẹ fi ìfẹ́ yín hàn sí wọn. Ẹ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òtítọ́ ni àwọn nǹkan tí a sọ fún wọn, tí a sì fi ọwọ́ rẹ̀ sọ̀yà nípa yín. Ẹ jẹ́ kí ó hàn sí gbogbo àwọn ìjọ bẹ́ẹ̀. Nípa ti ìrànlọ́wọ́ fún àwọn onigbagbọ, kò nílò pé kí n tún kọ ìwé si yín mọ́. Nítorí mo mọ àníyàn yín, mo sì ti ń fi ọwọ́ sọ̀yà nípa yín fún àwọn ará Masedonia, pé Akaya ti parí ètò tiwọn láti ọdún tí ó kọjá. Ìtara yín sì ti mú kí ọpọlọpọ túbọ̀ múra sí i. Mo rán àwọn arakunrin sí yín, kí ọwọ́ tí a fi ń sọ̀yà nípa yín lórí ọ̀rọ̀ yìí má baà jẹ́ lásán. Gẹ́gẹ́ bí mo ti sọ, kí ẹ ti múra sílẹ̀. Nítorí bí àwọn ará Masedonia bá bá mi wá sọ́dọ̀ yín, tí wọ́n wá rí i pé ẹ kò tíì múra sílẹ̀, ìtìjú ni yóo jẹ́ fún wa, kí á má wá sọ tiyín, nígbà tí a ti fi ọkàn tan yín lórí ọ̀rọ̀ yìí. Nítorí náà, mo rí i pé ó di dandan pé kí n bẹ àwọn arakunrin láti ṣiwaju mi wá sọ́dọ̀ yín, kí wọ́n ṣe ètò sílẹ̀ nípa ẹ̀bùn tí ẹ ti ṣe ìlérí, kí ó jẹ́ pé yóo ti wà nílẹ̀ kí n tó dé. Èyí yóo mú kí ó jẹ́ ọrẹ àtinúwá, kò ní jẹ́ ti ìlọ́ni-lọ́wọ́-gbà. Ẹ ranti pé ẹni tí ó bá fúnrúgbìn díẹ̀, díẹ̀ ni yóo kórè. Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn pupọ, pupọ ni yóo kórè. Kí olukuluku ṣe bí ó bá ti pinnu ninu ọkàn rẹ̀, kì í ṣe pẹlu ìkanra, tabi àfipáṣe, nítorí onínúdídùn ọlọ́rẹ ni Ọlọrun fẹ́. Ọlọrun lè fun yín ní oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn, tí ẹ óo fi ní ànító ninu ohun gbogbo nígbà gbogbo. Ẹ óo sì tún ní tí yóo ṣẹ́kù fún ohun rere gbogbo. Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ẹnìkan lawọ́, ó ń ta àwọn talaka lọ́rẹ, iṣẹ́ àánú rẹ̀ wà títí.” Ṣugbọn ẹni tí ó ń pèsè irúgbìn fún afunrugbin, tí ó tún ń pèsè oúnjẹ fún jíjẹ, yóo pèsè èso lọpọlọpọ fun yín, yóo sì mú kí àwọn èso iṣẹ́ àánú yín pọ̀ sí i. Ẹ óo jẹ́ ọlọ́rọ̀ ní gbogbo ọ̀nà tí ẹ óo fi lè máa lawọ́ nígbà gbogbo. Ọpọlọpọ eniyan yóo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nígbà tí a bá fún wọn ní ẹ̀bùn tí ẹ gbé kalẹ̀ nítorí ìlawọ́ yín. Nítorí kì í ṣe àìní àwọn onigbagbọ nìkan ni iṣẹ́ ìsìn yìí yóo pèsè fún, ṣugbọn yóo mú kí ọpọlọpọ eniyan máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun. Nítorí iṣẹ́ yìí jẹ́ ẹ̀rí tí àwọn eniyan yóo fi máa yin Ọlọrun fún rírẹ̀ tí ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ ní ìgbọràn gẹ́gẹ́ bí ìjẹ́wọ́ igbagbọ yín ninu ìyìn rere ti Kristi, ati nítorí ìlawọ́ yín ninu iṣẹ́ yìí fún wọn ati fún gbogbo onigbagbọ. Wọn yóo wá máa gbadura fun yín, ọkàn wọn yóo fà sọ́dọ̀ yín nítorí ọ̀pọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun lórí yín. Ọpẹ́ ni fún Ọlọrun nítorí ẹ̀bùn rẹ̀ tí kò ní òǹkà. Èmi Paulu fi ìrẹ̀lẹ̀ Kristi ati àánú rẹ̀ bẹ̀ yín, èmi tí ẹ̀ ń sọ pé nígbà tí mo bá wà lọ́dọ̀ yín mo jẹ́ eniyan jẹ́jẹ́, ṣugbọn nígbà tí mo bá kúrò lọ́dọ̀ yín mo di ògbójú si yín. Mo bẹ̀ yín, ẹ má ṣe jẹ́ kí n wá sọ́dọ̀ yín pẹlu ìgbójú, nítorí ó dá mi lójú pé mo lè ko àwọn kan, tí wọ́n sọ pé à ń hùwà bí ẹni tí ó ń wá ire ara wa lójú. Nítorí à ń gbé ìgbé-ayé wa ninu àìlera ti ara, ṣugbọn a kò jagun gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ń wá ire ara wa, nítorí àwọn ohun-ìjà wa kì í ṣe ti ayé, agbára Ọlọrun ni, tí a lè fi wó ìlú olódi. À ń bi gbogbo iyàn jíjà lórí èké ṣubú, ati gbogbo ìdínà tí ó bá gbórí sókè tí ó lòdì sí ìmọ̀ Ọlọrun. A mú gbogbo èrò ọkàn ní ìgbèkùn kí ó lè gbọ́ràn sí Kristi lẹ́nu. A sì ti múra tán láti jẹ gbogbo aláìgbọràn níyà, nígbà tí ẹ bá ti fi ara yín sábẹ́ wa. Nǹkan ti òde ara nìkan ni ẹ̀ ń wò! Bí ẹnikẹ́ni bá dá ara rẹ̀ lójú pé òun jẹ́ ti Kristi, kí ó tún inú ara rẹ̀ rò wò, nítorí bí ó ti jẹ́ ti Kristi, bẹ́ẹ̀ gan-an ni àwa náà jẹ́. Nítorí ojú kò tì mí bí mo bá ń ṣe ìgbéraga ní àṣejù nípa àṣẹ tí a ní, tí Oluwa fi fún mi, láti lè mu yín dàgbà ni, kì í ṣe láti fi bì yín ṣubú. N kò fẹ́ kí ẹ rò pé mò ń fi àwọn ìwé tí mò ń kọ dẹ́rù bà yín. Nítorí àwọn kan ń sọ pé, “Àwọn ìwé tí Paulu kọ jinlẹ̀, wọ́n sì le, ṣugbọn bí ẹ bá rí òun alára, bí ọlọ́kùnrùn ni ó rí, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì ta eniyan lára.” Kí ẹni tí ó bá ń rò báyìí mọ̀ pé bí a ti jẹ́ ninu ọ̀rọ̀ tí a kọ sinu ìwé nígbà tí a kò sí lọ́dọ̀ yín, bẹ́ẹ̀ náà ni a jẹ́ ninu iṣẹ́ wa nígbà tí a bá wà lọ́dọ̀ yín. Nítorí a kò gbọdọ̀ da ara wa mọ́ àwọn kan tí wọn ń yin ara wọn, tabi kí á fara wé wọn. Fúnra wọn ni wọ́n ṣe òṣùnwọ̀n tí wọ́n fi ń wọn ara wọn, àwọn tìkalára wọn náà ni wọ́n sì ń fi ara wọn wé. Wọn kò lóye. Ṣugbọn ní tiwa, a kò ní lérí ju bí ó ti yẹ lọ. Òṣùnwọ̀n wa kò tayọ ààlà tí Ọlọrun ti pa sílẹ̀ fún wa, tí a fi mú ìyìn rere dé ọ̀dọ̀ yín. Nítorí kì í ṣe pé a kọjá àyè wa nígbà tí a dé ọ̀dọ̀ yín, àwa ni a sì kọ́kọ́ mú ìyìn rere Kristi dé ọ̀dọ̀ yín. A kò gbọdọ̀ ṣe ìgbéraga pupọ ju bí ó ti yẹ lọ lórí iṣẹ́ àwọn ẹlòmíràn. A ní ìrètí pé bí igbagbọ yín ti ń dàgbà, bẹ́ẹ̀ ni ipò wa pẹlu yín yóo máa ga sí i, gẹ́gẹ́ bí ààyè wa. A óo wá mú ọ̀rọ̀ ìyìn rere kọjá ọ̀dọ̀ yín, láì ṣe ìgbéraga nípa iṣẹ́ tí ẹlòmíràn ti ṣe ní ààyè tirẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí yóo bá ṣe ìgbéraga, Oluwa ni kí ó fi ṣe ìgbéraga. Kì í ṣe ẹni tí ó yin ara rẹ̀ ni ó yege, bíkòṣe ẹni tí Oluwa bá yìn. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ gbà mí láyè kí n sọ̀rọ̀ díẹ̀ bí aṣiwèrè. Ẹ gbà mí láyè. Mò ń jowú nítorí yín, bí Ọlọrun tií jowú. Nítorí èmi ni mo ṣe ètò láti fà yín fún Kristi bí ẹni fa wundia tí ó pé fún ọkọ rẹ̀. Ẹ̀rù ń bà mí pé kí ẹ̀tàn má wọ inú ọkàn yín, tí ẹ óo fi yà kúrò ninu òtítọ́ ati ọkàn kan tí ẹ fi wà ninu Kristi, bí ejò ti fi àrékérekè rẹ̀ tan Efa jẹ. Nítorí ẹ̀ ń fi ààyè gba àwọn ẹlòmíràn tí wọn ń wá waasu Jesu yàtọ̀ sí bí a ti waasu rẹ̀, ẹ sì ń gba ìyìn rere mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti kọ́ gbà. N kò rò pé mo kéré sí àwọn tí wọn ń pe ara wọn ní “aposteli” pataki wọnyi! Ọ̀rọ̀ lè má dùn lẹ́nu mi, ṣugbọn mo ní ìmọ̀, ní ọ̀nà gbogbo a ti mú kí èyí hàn si yín ninu ohun gbogbo. Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ ni mo ṣẹ̀ tí mo fi ara mi sí ipò ìrẹ̀lẹ̀, kí ẹ lè ní ipò gíga? Àbí ẹ̀ṣẹ̀ ni, pé mo waasu ìyìn rere Ọlọrun fun yín láì gba nǹkankan lọ́wọ́ yín? Mo fẹ́rẹ̀ jẹ àwọn ìjọ mìíràn run, tí mò ń gba owó lọ́wọ́ wọn láti ṣe iṣẹ́ fun yín. Nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ yín, tí mo ṣe aláìní, n kò ni ẹnikẹ́ni lára, àwọn arakunrin tí ó wá láti Masedonia ni wọ́n mójútó àwọn ohun tí mo ṣe aláìní. Ninu gbogbo nǹkan, mo ṣe é lófin pé n kò ní wọ̀ yín lọ́rùn, n kò sì ní yí òfin yìí pada! Gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ Kristi ti wà ninu mi, kò sí ohun tí yóo mú mi yipada ninu ohun tí mo fi ń ṣe ìgbéraga ní gbogbo agbègbè Akaya. Nítorí kí ni? A máa ṣe pé n kò fẹ́ràn yín ni? Ọlọrun mọ̀ pé mo fẹ́ràn yín. Bí mo ti ń ṣe ni n óo tún máa ṣe, kí n má baà fi ààyè sílẹ̀ fún àwọn tí wọ́n fẹ́ ṣe ìgbéraga pé iṣẹ́ wọn dàbí tiwa. Aposteli èké ni irú àwọn bẹ́ẹ̀. Ẹlẹ́tàn ni wọ́n, tí wọn ń farahàn bí aposteli Kristi. Irú rẹ̀ kì í ṣe nǹkan ìjọjú, nítorí Satani pàápàá a máa farahàn bí angẹli ìmọ́lẹ̀. Nítorí náà, kò ṣòro fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ láti farahàn bí iranṣẹ tòótọ́. Ṣugbọn ìgbẹ̀yìn wọn yóo rí bí iṣẹ́ wọn. Mo tún wí lẹ́ẹ̀kan sí i, kí ẹnikẹ́ni má ṣe rò pé aṣiwèrè ni mí. Ṣugbọn bí ẹ bá rò bẹ́ẹ̀, ẹ sá gbà mí bí aṣiwèrè, kí n lè fọ́nnu díẹ̀. N kò sọ̀rọ̀ bí onigbagbọ nípa ohun tí mo fi ń fọ́nnu yìí, bí aṣiwèrè ni mò ń sọ̀rọ̀. Ọpọlọpọ ní ń fọ́nnu nípa nǹkan ti ara, ẹ jẹ́ kí èmi náà fọ́nnu díẹ̀! Pẹlu ayọ̀ ni ẹ fi ń gba àwọn aṣiwèrè, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n! Bí ẹnìkan bá ń lò yín bí ẹrú, tí ó ń jẹ yín run, tí ó fi okùn mu yín, tí ó ń ṣe fùkẹ̀ láàrin yín, tí ó ń gba yín létí, ẹ ṣetán láti gba irú ẹni bẹ́ẹ̀. Ojú tì mí láti gbà pé àwa kò lágbára tó láti hu irú ìwà bẹ́ẹ̀! Ṣugbọn bí ẹnìkan bá láyà láti fi ohun kan ṣe ìgbéraga, ẹ jẹ́ kí n sọ̀rọ̀ bí aṣiwèrè, èmi náà láyà láti ṣe ìgbéraga. Ṣé Heberu ni wọ́n ni? Heberu ni èmi náà. Ọmọ Israẹli ni wọ́n? Bẹ́ẹ̀ ni èmi náà. Ṣé ìdílé Abrahamu ni wọ́n? Òun ni èmi náà. Iranṣẹ Kristi ni wọ́n? Tí n óo bá sọ̀rọ̀ bí ẹni tí orí rẹ̀ kò pé, mo jù wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí iranṣẹ Kristi. Mo ti fi agbára ṣiṣẹ́ jù wọ́n lọ. Mo ti wẹ̀wọ̀n nígbà pupọ jù wọ́n lọ. Wọ́n ti nà mí nígbà pupọ jù wọ́n lọ. Ẹ̀mí fẹ́rẹ̀ bọ́ lẹ́nu mi ní ọpọlọpọ ìgbà. Ẹẹmarun-un ni àwọn Juu nà mí ní ẹgba mọkandinlogoji. Ẹẹmẹta ni a fi ọ̀pá lù mí. A sọ mí lókùúta lẹ́ẹ̀kan. Ẹẹmẹta ni ọkọ̀ ojú omi tí mo wọ̀ rì. Fún odidi ọjọ́ kan, tọ̀sán-tòru, ni mo fi wà ninu agbami. Ní ọpọlọpọ ìgbà ni mo wà lórí ìrìn àjò, tí mo wà ninu ewu omi, ewu lọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà, ewu láàrin àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ mi, ewu láàrin àwọn tíí ṣe Juu, ewu ninu ìlú, ewu ninu oko, ewu lójú òkun, ati ewu láàrin àwọn èké onigbagbọ. Mo ti rí ọ̀pọ̀ wahala ati ìṣòro. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni n kò lè sùn. Ebi pa mí, òùngbẹ gbẹ mí. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mò ń gbààwẹ̀. Mo mọ ìgbà òtútù ati ìgbà tí aṣọ kò tó láti fi bora. Láì ka àwọn nǹkan mìíràn tí n kò mẹ́nubà, lojoojumọ ni àníyàn gbogbo àwọn ìjọ wúwo lọ́kàn mi. Ta ni jẹ́ aláìlera tí n kò ní ìpín ninu àìlera rẹ̀? Ta ni ṣubú sinu ẹ̀ṣẹ̀ tí ọkàn mi kò bàjẹ́? Bí mo bá níláti fọ́nnu, n óo fọ́nnu nípa àwọn àìlera mi. Ọlọrun Baba Oluwa wa Jesu, ẹni tí ìyìn yẹ fún títí lae, mọ̀ pé n kò purọ́. Ní Damasku, baálẹ̀ tí ó wà lábẹ́ Ọba Areta ń ṣọ́ ẹnu odi ìlú láti mú mi. Apẹ̀rẹ̀ ni wọ́n fi sọ̀ mí kalẹ̀ láti ojú fèrèsé lára odi ìlú, ni mo fi bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Ó yẹ kí n fọ́nnu. Rere kan kò ti ibẹ̀ wá, sibẹ n óo sọ ti ìran ati ìfarahàn Oluwa. Mo mọ ọkunrin onigbagbọ kan ní ọdún mẹrinla sẹ́yìn. Bí ó wà ninu ara ni o, bí ó rí ìran ni o, èmi kò mọ̀–Ọlọrun ni ó mọ̀. A gbé ọkunrin yìí lọ sí ọ̀run kẹta. Mo mọ ọkunrin yìí, bí ninu ara ni o, bí lójú ìran ni o, èmi kò mọ̀–Ọlọrun ni ó mọ̀. A gbé e lọ sí Paradise níbi tí ó gbé gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí kò ṣe é sọ, ọ̀rọ̀ àṣírí tí kò gbọdọ̀ jáde lẹ́nu eniyan. *** N óo fọ́nnu nípa irú ọkunrin bẹ́ẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò ní fọ́nnu nípa ara tèmi ati nípa àwọn àìlera mi. Bí mo bá fẹ́ fọ́nnu, kò ní jẹ́ ọ̀rọ̀ aṣiwèrè ni n óo sọ; òtítọ́ ni n óo sọ. Ṣugbọn n kò ní ṣe bẹ́ẹ̀, kí ẹnikẹ́ni má baà rò nípa mi ju ohun tí ó rí ninu ìwà mi ati ohun tí ó gbọ́ lẹ́nu mi lọ. Nítorí náà, kí n má baà ṣe ìgbéraga nípa àwọn ìfihàn tí ó ga pupọ wọnyi, a fi ẹ̀gún kan sí mi lára, ẹ̀gún yìí jẹ́ iranṣẹ Satani, láti máa gún mi, kí n má baà gbéraga. Ẹẹmẹta ni mo bẹ Oluwa nítorí rẹ̀ pé kí ó mú un kúrò lára mi. Ìdáhùn tí ó fún mi ni pé, “Oore-ọ̀fẹ́ mi tó fún ọ. Ninu àìlera rẹ ni agbára mi di pípé.” Nítorí náà ninu àwọn ohun tí ó jẹ́ àìlera fún mi ni mo ní ayọ̀ pupọ jùlọ, àwọn ni n óo fi ṣe ìgbéraga, kí agbára Kristi lè máa bá mi gbé. Nítorí èyí mo ní inú dídùn ninu àìlera mi, ati ninu àwọn ìwọ̀sí, ìṣòro, inúnibíni ati ìpọ́njú tí mo ti rí nítorí ti Kristi. Nítorí nígbà tì mo bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára. Mo ti di aṣiwèrè! Ẹ̀yin ni ẹ sì sọ mí dà bẹ́ẹ̀. Nítorí ìyìn ni ó yẹ kí n gbà lọ́dọ̀ yín. Nítorí bí n kò tilẹ̀ jẹ́ nǹkankan, n kò rẹ̀yìn ninu ohunkohun sí àwọn aposteli yín tí ẹ kà kún pataki. Àwọn àmì aposteli hàn ninu iṣẹ́ mi láàrin yín nípa oríṣìíríṣìí ìfaradà, nípa iṣẹ́ abàmì, iṣẹ́ ìyanu, ati iṣẹ́ agbára. Ọ̀nà wo ni a fi ba yín lò tí ó burú ju ti àwọn ìjọ ìyókù lọ; àfi ti pé èmi fúnra mi kò ni yín lára? Ẹ forí jì mí fún àṣìṣe yìí! Ẹ wò ó! Ẹẹkẹta nìyí tí mo múra tán láti wá sọ́dọ̀ yín. N kò sì ní ni yín lára. Nítorí kì í ṣe àwọn nǹkan dúkìá yín ni mo fẹ́ bíkòṣe ẹ̀yin fúnra yín. Nítorí kì í ṣe àwọn ọmọ ni ó yẹ láti pèsè fún àwọn òbí wọn. Àwọn òbí ni ó yẹ kí ó pèsè fún àwọn ọmọ. Ní tèmi, pẹlu ayọ̀ ni ǹ bá fi náwó-nára patapata fún ire ọkàn yín. Bí èmi bá fẹ́ràn yín pupọ, ṣé díẹ̀ ni ó yẹ kí ẹ̀yin fẹ́ràn mi? Ẹ gbà pé n kò ni yín lára. Ṣugbọn àwọn kan rò pé ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ ni mí, ati pé ẹ̀tàn ni mo fi mu yín. Ninu àwọn tí mo rán si yín, èwo ni mo lò láti fi rẹ yín jẹ? Mo bẹ Titu kí ó wá sọ́dọ̀ yín. Mo tún rán arakunrin wa pẹlu rẹ̀. Ǹjẹ́ Titu rẹ yín jẹ bí? Ṣebí Ẹ̀mí kan náà ni ó ń darí wa? Tabi kì í ṣe ọ̀nà kan náà ni a jọ ń ṣiṣẹ́? Ṣé ohun tí ẹ ti ń rò ni pé à ń wí àwíjàre níwájú yín? Rárá o! Níwájú Ọlọrun, gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ ni à ń sọ̀rọ̀. Ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, gbogbo nǹkan tí à ń ṣe, fún ìdàgbàsókè yín ni. Nítorí ẹ̀rù ń bà mí pé nígbà ti mo bá dé, mo lè má ba yín ní irú ipò tí mo fẹ́, ati pé ẹ̀yin náà lè rí i pé n kò rí bí ẹ ti ń rò. Ẹ̀rù ń bà mí pé kí ohun tí n óo bá láàrin yín má jẹ́ ìjà ati owú jíjẹ, ibinu ati ìwà ọ̀kánjúwà, ọ̀rọ̀ burúkú ati ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìgbéraga ati ìrúkèrúdò. Ẹ̀rù ń bà mí pé nígbà tí mo bá tún dé, kí Ọlọrun mi má dójú tì mí níwájú yín, kí n má ní ìbànújẹ́ nítorí ọpọlọpọ tí wọ́n ti ṣẹ̀ tẹ́lẹ̀ tí wọn kò ronupiwada kúrò ninu ìṣekúṣe, àgbèrè ati ìwà wọ̀bìà tí wọ́n ti ń hù. Ẹẹkẹta nìyí tí n óo wá sọ́dọ̀ yín. Lẹ́nu ẹlẹ́rìí meji tabi mẹta ni a óo sì ti mọ òtítọ́ gbogbo ọ̀rọ̀. Gẹ́gẹ́ bí mo ti sọ fún àwọn tí wọ́n ti ṣẹ̀ tẹ́lẹ̀ ati àwọn yòókù, tí mo tún sọ nígbà tí mo wá sọ́dọ̀ yín lẹẹkeji, bẹ́ẹ̀ ni mo tún ń sọ nisinsinyii tí n kò sí lọ́dọ̀ yín, pé nígbà tí mo bá tún dé, n kò ní ṣojú àánú; nígbà tí ó ti jẹ́ pé ẹ̀rí ni ẹ̀ ń wá pé Kristi ń lò mí láti sọ̀rọ̀. Kristi kì í ṣe aláìlera ninu ìbálò rẹ̀ pẹlu yín. Òtítọ́ ni pé a kàn án mọ́ agbelebu ní àìlera, ṣugbọn ó wà láàyè nípa agbára Ọlọrun. Òtítọ́ ni pé àwa náà jẹ́ aláìlera pẹlu rẹ̀, ṣugbọn a óo wà láàyè pẹlu rẹ̀ nípa agbára Ọlọrun ninu ìbálò wa pẹlu yín. Ẹ yẹ ara yín wò bí ẹ bá ń gbé ìgbé-ayé ti igbagbọ. Ẹ yẹ ara yín wò. Àbí ẹ̀yin fúnra yín kò mọ̀ pé Kristi Jesu wà ninu yín? Àfi bí ẹ bá ti kùnà nígbà tí ẹ yẹ ara yín wò! Ṣugbọn mo ní ìrètí pé ẹ mọ̀ pé ní tiwa, àwa kò kùnà. À ń gbadura sí Ọlọrun pé kí ẹ má ṣe nǹkan burúkú kan, kì í ṣe pé nítorí kí á lè farahàn bí ẹni tí kò kùnà, ṣugbọn kí ẹ̀yin lè máa ṣe rere, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa dàbí ẹni tí ó kùnà. Nítorí a kò lè ṣe nǹkankan tí ó lòdì sí òtítọ́, àfi òtítọ́. Nítorí náà inú wa dùn nígbà tí àwa bá jẹ́ aláìlera, tí ẹ̀yin sì jẹ́ alágbára. Èyí ni à ń gbadura fún, pé kí ẹ tún ìgbé-ayé yín ṣe. Ìdí tí mo fi ń kọ gbogbo nǹkan wọnyi nígbà tí n kò sí lọ́dọ̀ yín ni pé nígbà tí mo bá dé, kí n má baà fi ìkanra lo àṣẹ tí Oluwa ti fi fún mi láti fi mú ìdàgbà wá, kì í ṣe láti fi wo yín lulẹ̀. Ní ìparí, ẹ̀yin ará, ó dìgbà! Ẹ tún ọ̀nà yín ṣe. Ẹ gba ìkìlọ̀ wa. Ẹ ní ọkàn kan náà láàrin ara yín. Ẹ máa gbé pọ̀ ní alaafia. Ọlọrun ìfẹ́ ati alaafia yóo wà pẹlu yín. Ẹ fi ìfẹnukonu ti alaafia kí ara yín. Gbogbo àwọn onigbagbọ ki yín. Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa Jesu Kristi, ati ìfẹ́ Ọlọrun ati ìdàpọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ wà pẹlu gbogbo yín. Èmi Paulu, kì í ṣe eniyan ni ó pè mí láti jẹ́ aposteli, n kò sì ti ọ̀dọ̀ eniyan gba ìpè, Jesu Kristi ati Ọlọrun Baba, tí ó jí Jesu dìde, ni ó pè mí. Èmi ati gbogbo arakunrin tí ó wà lọ́dọ̀ mi ni à ń kọ ìwé yìí sí àwọn ìjọ Galatia. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia Ọlọrun, Baba wa, wà pẹlu yín ati ti Oluwa Jesu Kristi, ẹni tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí ó lè gbà wá kúrò lọ́wọ́ ayé wa burúkú yìí, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọrun Baba wa, ẹni tí ògo yẹ fún lae ati laelae. Amin. Ẹnu yà mí pé ẹ ti kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó pè yín nípa oore-ọ̀fẹ́ Kristi, ẹ ti yára yipada sí ìyìn rere mìíràn. Kò sí ìyìn rere mìíràn ju pé àwọn kan wà tí wọn ń yọ yín lẹ́nu, tí wọ́n fẹ́ yí ìyìn rere Kristi pada. Ṣugbọn bí àwa fúnra wa tabi angẹli láti ọ̀run bá waasu ìyìn rere mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí a ti waasu fun yín, kí olúwarẹ̀ di ẹni ègbé. Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀, mo tún ń wí nisinsinyii pé bí ẹnikẹ́ni bá waasu ìyìn rere mìíràn fun yín, yàtọ̀ sí èyí tí ẹ gbà, kí olúwarẹ̀ di ẹni ègbé. Ṣé ojurere eniyan ni mò ń wá nisinsinyii, tabi ti Ọlọrun? Àbí ohun tí ó wu eniyan ni mo fẹ́ máa ṣe? Bí ó bá jẹ́ pé ohun tí ó wu eniyan ni mò ń ṣe sibẹ, èmi kì í ṣe iranṣẹ Kristi. Ẹ̀yin ará, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ìyìn rere tí mò ń waasu kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ eniyan. Kì í ṣe ọwọ́ eniyan ni mo ti gbà á, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe eniyan ni ó kọ́ mi. Jesu Kristi ni ó fihàn mí. Nítorí ẹ ti gbúròó ìwà mi látijọ́ nígbà tí mo wà ninu ẹ̀sìn ti Juu, pé mò ń fìtínà ìjọ Ọlọrun ju bí ó ti yẹ lọ. Mo sa gbogbo ipá mi láti pa á run. Ninu ẹ̀sìn Juu, mo ta ọpọlọpọ àwọn ẹlẹgbẹ́ mi ninu orílẹ̀-èdè mi yọ. Mo ní ìtara rékọjá ààlà ninu àṣà ìbílẹ̀ àwọn baba-ńlá mi. Ṣugbọn nígbà tí ó wu Ọlọrun, tí ó ti yà mí sọ́tọ̀ láti inú ìyá mi, ó fi oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ pè mí, láti fi Ọmọ rẹ̀ hàn ninu mi, kí n lè máa waasu ìyìn rere rẹ̀ láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu. Nígbà tí ó pè mí, n kò bá ẹnikẹ́ni gbèrò, n kò gòkè lọ sí Jerusalẹmu sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n jẹ́ aposteli ṣiwaju mi, ṣugbọn mo lọ sí ilẹ̀ Arabia, láti ibẹ̀ ni mo tún ti pada sí Damasku. Lẹ́yìn ọdún mẹta ni mo tó gòkè lọ sí Jerusalẹmu láti lọ rí Peteru, mo sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ fún ọjọ́ mẹẹdogun. Kò tún sí ọ̀kan ninu àwọn aposteli yòókù tí mo rí àfi Jakọbu arakunrin Oluwa. Mo fi Ọlọrun jẹ́rìí pé kò sí irọ́ ninu ohun tí mò ń kọ si yín yìí! Lẹ́yìn náà mo lọ sí agbègbè Siria ati ti Silisia. Àwọn ìjọ Kristi tí ó wà ní Judia kò mọ̀ mí sójú. Ṣugbọn wọ́n ń gbọ́ pé, “Ẹni tí ó ti ń fìtínà wa tẹ́lẹ̀ rí ti ń waasu ìyìn rere igbagbọ tí ó fẹ́ parun nígbà kan rí.” Wọ́n bá ń yin Ọlọrun lógo nítorí mi. Lẹ́yìn ọdún mẹrinla ni mo tó tún gòkè lọ sí Jerusalẹmu pẹlu Banaba. Mo mú Titu lọ́wọ́ pẹlu. Ọlọrun ni ó fihàn mí lójúran ni mo fi lọ. Mo wá ṣe àlàyé níwájú àwọn aṣaaju nípa ìyìn rere tí mò ń waasu fún àwọn tí kì í ṣe Juu. Níkọ̀kọ̀ ni a sọ̀rọ̀ kí gbogbo iré-ìje tí mò ń sá ati èyí tí mo ti sá má baà jẹ́ lásán. Kì í ṣe ọ̀ranyàn ni pé kí á kọ Titu tí ó wà pẹlu mi nílà nítorí pé ọmọ ẹ̀yà Giriki ni. Àwọn tí ó gbé ọ̀rọ̀ nípa ìkọlà Titu jáde ni àwọn arakunrin èké tí wọ́n yọ́ wá wo òmìnira wa tí a ní ninu Kristi Jesu, kí wọ́n lè sọ wá di ẹrú òfin. Ṣugbọn a kò fi ìgbà kankan gbà wọ́n láyè rárá, kí ó má dàbí ẹni pé ọ̀rọ̀ tiwọn ni ó borí, kí òtítọ́ ìyìn rere lè wà pẹlu yín. Ṣugbọn àwọn tí wọn ń pè ní aṣaaju ninu wọn kò kọ́ mi ní ohun titun kan. Ohun tí ó mú kí n sọ̀rọ̀ báyìí ni pé kò sí ohun tí ó kàn mí ninu ọ̀rọ̀ a-jẹ́-aṣaaju tabi a-kò-jẹ́-aṣaaju. Ọlọrun kì í ṣe ojuṣaaju. Ṣugbọn wọ́n wòye pé a ti fi iṣẹ́ ajíyìnrere fún àwọn aláìkọlà fún mi ṣe, gẹ́gẹ́ bí a ti fún Peteru ní iṣẹ́ ajíyìnrere fún àwọn tí ó kọlà. Nítorí ẹni tí ó fún Peteru ní agbára láti ṣiṣẹ́ láàrin àwọn tí wọ́n kọlà ni ó fún mi ní agbára láti ṣiṣẹ́ láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu. Nígbà tí Jakọbu, Peteru ati Johanu, tí àwọn eniyan ń wò bí òpó ninu ìjọ, rí oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun ti fi fún mi, wọ́n bọ èmi ati Banaba lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí àmì ìdàpọ̀, wọ́n ní kí àwa lọ sáàrin àwọn tí kì í ṣe Juu bí àwọn náà ti ń lọ sáàrin àwọn tí ó kọlà. Nǹkankan ni wọ́n sọ fún wa, pé kí á ranti àwọn talaka láàrin àwọn tí ó kọlà. Òun gan-an ni mo sì ti dàníyàn láti máa ṣe. Ṣugbọn nígbà tí Peteru wà ní Antioku, mo takò ó lojukooju nítorí ó ṣe ohun ìbáwí. Nítorí kí àwọn kan tó ti ọ̀dọ̀ Jakọbu dé, Peteru ti ń bá àwọn onigbagbọ tí kì í ṣe Juu jẹun. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé, ó bẹ̀rẹ̀ sí fà sẹ́yìn, ó ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀, nítorí ó ń bẹ̀rù àwọn tí wọ́n fẹ́ kí gbogbo onigbagbọ kọlà. Àwọn Juu yòókù bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àgàbàgebè pẹlu Peteru. Wọ́n tilẹ̀ mú Banaba pàápàá wọ ẹgbẹ́ àgàbàgebè wọn! Nígbà tí mo rí i pé ohun tí wọn ń ṣe kò bá òtítọ́ ìyìn rere mu, mo wí fún Peteru níwájú gbogbo wọn pé, “Bí ìwọ tí ó jẹ́ Juu bá ti ń ṣe bí àwọn yòókù, tí o kò ṣe bí àṣà àwọn Juu, kí ló dé tí o fi fẹ́ kí àwọn tí kì í ṣe Juu ṣe ara wọn bíi Juu?” Àwa tí a bí ní Juu, tí a kì í ṣe ti àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí ó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, mọ̀ pé kò sí ẹnikẹ́ni tí Ọlọrun yóo dá láre nípa iṣẹ́ òfin, àfi nípa igbagbọ ninu Jesu Kristi. Àwa pàápàá gba Kristi Jesu gbọ́, kí Ọlọrun lè dá wa láre nípa igbagbọ ninu rẹ̀, kì í ṣe nípa iṣẹ́ òfin. Nígbà tí à ń wá ọ̀nà ìdáláre ninu Kristi, bí a bá rí i pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni àwa náà, ṣé Kristi wá di iranṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ ni? Rárá o! Nítorí bí ó bá jẹ́ pé àwọn ohun tí mo ti wó lulẹ̀ ni mo tún ń kọ́, èmi náà di ẹlẹ́ṣẹ̀. Nítorí nípa òfin, mo ti kú sinu òfin kí n lè wà láàyè lọ́dọ̀ Ọlọrun. A ti kàn mí mọ́ agbelebu pẹlu Kristi. Mo wà láàyè, ṣugbọn kì í ṣe èmi ni mo wà láàyè; Kristi ni ó ń gbé inú mi. Ìgbé-ayé tí mò ń gbé ninu ara nisinsinyii, nípa igbagbọ ninu Ọmọ Ọlọrun tí ó fẹ́ràn mi ni. Ó fẹ́ràn mi tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí mi. Kì í ṣe pé mo pa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun tì. Nítorí bí eniyan bá lè di olódodo nípa ṣíṣe iṣẹ́ òfin, a jẹ́ pé Kristi kàn kú lásán ni. Ẹ̀yin ará Galatia, ẹ mà kúkú gọ̀ o! Ta ni ń dì yín rí? Ẹ̀yin tí a gbé Jesu Kristi tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu sí níwájú gbangba! Nǹkankan péré ni mo fẹ́ bi yín: ṣé nípa iṣẹ́ òfin ni ẹ fi gba Ẹ̀mí ni tabi nípa ìgbọràn igbagbọ? Àṣé ẹ ṣiwèrè tóbẹ́ẹ̀! Ẹ bẹ̀rẹ̀ pẹlu nǹkan ti ẹ̀mí, ẹ wá fẹ́ fi nǹkan ti ara parí! Gbogbo ìyà tí ẹ ti jẹ á wá jẹ́ lásán? Kò lè jẹ́ lásán! Ṣé nítorí pé ẹ̀ ń ṣe iṣẹ́ òfin ni ẹni tí ó fi ẹ̀bùn Ẹ̀mí fun yín ṣe fun yín lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, tí ó tún ṣiṣẹ́ ìyanu láàrin yín, tabi nítorí pé ẹ gbọ́ ìyìn rere, ẹ sì gbà á? Bí Abrahamu ti gba Ọlọrun gbọ́, tí Ọlọrun wá gbà á gẹ́gẹ́ bí olódodo, kí ó ye yín pé àwọn ẹni tí ó bá gbàgbọ́ ni ọmọ Abrahamu. Ìwé Mímọ́ ti sọ tẹ́lẹ̀ pé nípa igbagbọ ni Ọlọrun yóo fi dá àwọn tí kì í ṣe Juu láre, ó waasu ìyìn rere fún Abrahamu pé, “Gbogbo àwọn tí kì í ṣe Juu yóo di ẹni ibukun nípasẹ̀ rẹ.” Èyí ni pé àwọn tí ó gbàgbọ́ rí ibukun gbà, bí Abrahamu ti rí ibukun gbà nítorí pé ó gbàgbọ́. A ti fi gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé iṣẹ́ òfin gégùn-ún. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ègbé ni fún gbogbo ẹni tí kò bá máa ṣe ohun gbogbo tí a kọ sinu ìwé òfin.” Ó dájú pé kò sí ẹnikẹ́ni tí Ọlọrun yóo dá láre nípa òfin, nítorí a kà á pé, “Olódodo yóo wà láàyè nípa igbagbọ.” Ṣugbọn òfin kì í ṣe igbagbọ, nítorí a kà á pé, “Ẹni tí ó bá ń pa gbogbo òfin mọ́ yóo wà láàyè nípa wọn.” Kristi ti rà wá pada kúrò lábẹ́ ègún òfin, ó ti di ẹni ègún nítorí tiwa, nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ègbé ni fún gbogbo ẹni tí wọ́n bá gbé kọ́ sórí igi.” Ìdí rẹ̀ ni pé kí ibukun Abrahamu lè kan àwọn tí kì í ṣe Juu nípasẹ̀ Kristi Jesu, kí á lè gba ìlérí Ẹ̀mí nípa igbagbọ. Ẹ̀yin ará, ẹ jẹ́ kí á lo àkàwé kan ninu ìrírí eniyan. Gẹ́gẹ́ bí àṣà, nígbà tí a bá ti ṣe majẹmu tán, kò sí ẹni tí ó lè yí i pada tabi tí ó lè fi gbolohun kan kún un. Nígbà tí Ọlọrun ṣe ìlérí fún Abrahamu ati irú-ọmọ rẹ̀, kì í ṣe ọ̀rọ̀ gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ ni Ọlọrun ń sọ, ṣugbọn ọmọ kanṣoṣo ni ó tọ́ka sí. Ó sọ pé, “Ati fún irú-ọmọ rẹ.” Ọmọ náà ni Kristi. Kókó ohun tí mò ń sọ ni pé òfin tí ó dé lẹ́yìn ọgbọnlenirinwo (430) ọdún kò lè pa majẹmu tí Ọlọrun ti ṣe rẹ́. Ìlérí tí Ọlọrun ti ṣe kò lè torí rẹ̀ di òfo. Nítorí bí eniyan bá lè di ajogún nípa òfin, a jẹ́ pé kì í tún ṣe ìlérí mọ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni nípa ìlérí ni Ọlọrun fún Abrahamu ní ogún. Ipò wo wá ni òfin wà? Kí eniyan lè mọ ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́ṣẹ̀ ni Ọlọrun ṣe fi òfin kún ìlérí, títí irú-ọmọ tí ó ṣe ìlérí rẹ̀ fún yóo fi dé. Láti ọwọ́ àwọn angẹli ni alárinà ti gba òfin. Ètò tí alárinà bá lọ́wọ́ sí ti kúrò ní ti ẹyọ ẹnìkan. Ṣugbọn ọ̀kan ṣoṣo ni Ọlọrun. Ǹjẹ́ òfin wá lòdì sí àwọn ìlérí Ọlọrun ni bí? Rárá o! Bí ó bá jẹ́ pé òfin tí a fi fúnni lè sọ eniyan di alààyè, eniyan ìbá lè di olódodo nípa òfin. Ṣugbọn Ìwé Mímọ́ ti sọ pé ohun gbogbo wà ninu ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀ kí á lè fi ìlérí nípa igbagbọ ninu Jesu Kristi fún gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́. Ṣugbọn kí àkókò igbagbọ yìí tó tó, a wà ninu àtìmọ́lé lábẹ́ òfin, a sé wa mọ́ títí di àkókò igbagbọ yìí. Èyí ni pé òfin jẹ́ olùtọ́ wa títí Kristi fi dé, kí á lè dá wa láre nípa igbagbọ. Nígbà tí àkókò igbagbọ ti dé, a kò tún nílò olùtọ́ mọ́. Nítorí gbogbo yín jẹ́ ọmọ Ọlọrun nípa igbagbọ ninu Kristi Jesu. Nítorí gbogbo ẹni tí ó ti ṣe ìrìbọmi nípa igbagbọ ninu Kristi ti gbé Kristi wọ̀. Kò tún sí ọ̀rọ̀ pé ẹnìkan ni Juu, ẹnìkan ni Giriki mọ́, tabi pé ẹnìkan jẹ́ ẹrú tabi òmìnira, ọkunrin tabi obinrin. Nítorí gbogbo yín ti di ọ̀kan ninu Kristi Jesu. Tí ẹ bá jẹ́ ti Kristi, a jẹ́ pé ẹ jẹ́ irú-ọmọ Abrahamu, ẹ sì di ajogún ìlérí. Ohun tí mò ń sọ ni pé nígbà tí àrólé bá wà ní ọmọde kò sàn ju ẹrú lọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni ó ni gbogbo nǹkan tí Baba rẹ̀ fi sílẹ̀. Nítorí pé òun alára wà lábẹ́ àwọn olùtọ́jú, ohun ìní rẹ̀ sì wà ní ìkáwọ́ àwọn alámòójútó títí di àkókò tí baba rẹ̀ ti dá. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí pẹlu wa. Nígbà tí a jẹ́ ọmọde, a jẹ́ ẹrú àwọn oríṣìíríṣìí ẹ̀mí tí a kò fojú rí. Ṣugbọn nígbà tí ó tó àkókò tí ó wọ̀, Ọlọrun rán Ọmọ rẹ̀ wá. Obinrin ni ó bí i, ó bí i lábẹ́ òfin àwọn Juu, kí ó lè ra àwọn tí ó wà lábẹ́ òfin pada, kí á lè sọ wá di ọmọ. Ọlọrun rán ẹ̀mí ọmọ rẹ̀ sinu ọkàn wa, Ẹ̀mí yìí ń ké pé, “Baba!” láti fihàn pé ọmọ ni ẹ jẹ́. Nítorí náà, ẹ kì í ṣe ẹrú mọ́ bíkòṣe ọmọ. Bí ẹ bá wá jẹ́ ọmọ, ẹ di ajogún nípasẹ̀ iṣẹ́ Ọlọrun. Ṣugbọn nígbà tí ẹ kò mọ Ọlọrun, ẹ di ẹrú àwọn ẹ̀dá tí kì í ṣe Ọlọrun. Nisinsinyii ẹ mọ Ọlọrun, tabi kí á kúkú wí pé Ọlọrun mọ̀ yín. Báwo ni ẹ ṣe tún fẹ́ yipada sí àwọn ẹ̀mí tí a kò fi ojú rí, tí wọ́n jẹ́ aláìlera ati aláìní, tí ẹ tún fẹ́ máa lọ ṣe ẹrú wọn? Ẹ̀ ń ya oríṣìíríṣìí ọjọ́ sọ́tọ̀, ẹ̀ ń ranti oṣù titun, àkókò ati àjọ̀dún! Ẹ̀rù yín ń bà mí pé kí gbogbo làálàá mi lórí yín má wá jẹ́ lásán! Ẹ̀yin ará, mo bẹ̀ yín ni, ẹ dàbí mo ti dà nítorí èmi náà ti dàbí yín. Ẹ kò ṣẹ̀ mí rárá. Ẹ mọ̀ pé àìlera ni ó mú kí n waasu ìyìn rere fun yín ní àkọ́kọ́. Ẹ kò kọ ohun tí ó jẹ́ ìdánwò fun yín ninu ara mi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò fi mí ṣẹ̀sín, ṣugbọn ẹ gbà mí bí ẹni pé angẹli Ọlọrun ni mí, àní bí ẹni pé èmi ni Kristi Jesu. Kò sí bí inú yín kò ti dùn tó nígbà náà. Kí ni ó wá dé nisinsinyii! Nítorí mo jẹ́rìí yín pé bí ó bá ṣeéṣe nígbà náà ẹ̀ bá yọ ojú yín fún mi! Mo wá ti di ọ̀tá yín nítorí mo sọ òtítọ́ fun yín! Kì í ṣe ire yín ni àwọn tí wọn ń ṣaájò yín ń wá. Ohun tí wọn ń wá ni kí wọ́n lè fi yín sinu àhámọ́, kí ẹ lè máa wá wọn. Ó dára kí á máa wá ara ẹni ninu ohun rere nígbà gbogbo, kì í ṣe nígbà tí mo bá wà pẹlu yín nìkan. Ẹ̀yin ọmọ mi, ara ń ni mí nítorí yín, bí obinrin tí ń rọbí lọ́wọ́, títí ẹ óo fi di àwòrán Kristi. Ó wù mí bíi pé kí n wà lọ́dọ̀ yín nisinsinyii, kí n yí ohùn mi pada, nítorí ọ̀rọ̀ yín rú mi lójú. Ẹ sọ fún mi, ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ wà lábẹ́ òfin: ṣé ẹ gbọ́ ohun tí òfin wí? Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé Abrahamu ní ọmọ meji, ọ̀kan ọmọ ẹrubinrin, ọ̀kan ọmọ obinrin tí ó ní òmìnira. Ó bí ọmọ ti ẹrubinrin nípa ìfẹ́ ara, ṣugbọn ó bí ọmọ ti obinrin tí ó ní òmìnira nípa ìlérí Ọlọrun. Àkàwé ni nǹkan wọnyi. Obinrin mejeeji yìí jẹ́ majẹmu meji, ọ̀kan láti òkè Sinai, tí ọmọ rẹ̀ jẹ́ ẹrú; èyí ni Hagari. Hagari ni òkè Sinai ní Arabia tíí ṣe àpẹẹrẹ Jerusalẹmu ti òní. Ó wà ninu ipò ẹrú pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀. Ṣugbọn Jerusalẹmu ti òkè wà ninu òmìnira. Òun ni ìyá wa. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Máa yọ̀, ìwọ àgàn tí kò bímọ rí. Sọ̀rọ̀ kí o kígbe sókè, ìwọ tí kò rọbí rí. Nítorí àwọn ọmọ àgàn pọ̀ ju ti obinrin tí ó ní ọkọ lọ.” Ṣugbọn ẹ̀yin, ará, ọmọ ìlérí bíi Isaaki ni yín. Ṣugbọn bí ó ti rí látijọ́, tí ọmọ tí a bí nípa ìfẹ́ ara ń ṣe inúnibíni ọmọ tí a bí nípa Ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ náà ni ó wà títí di ìsinsìnyìí. Ṣugbọn kí ni Ìwé Mímọ́ wí? Ó ní, “Lé ẹrubinrin ati ọmọ rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ẹrubinrin kò ní bá ọmọ obinrin tí ó ní òmìnira pín ogún baba wọn.” Nítorí náà, ará, a kì í ṣe ọmọ ẹrubinrin, ọmọ obinrin tí ó ní òmìnira ni wá. Irú òmìnira yìí ni a ní. Kristi ti sọ wá di òmìnira. Ẹ dúró ninu rẹ̀, kí ẹ má sì tún gbé àjàgà ẹrú kọ́rùn mọ́. Èmi Paulu ni mo wí fun yín pé bí ẹ bá kọlà, Kristi kò ṣe yín ní anfaani kankan. Mo tún wí pé gbogbo ẹni tí a bá kọ nílà di ajigbèsè; ó níláti pa gbogbo òfin mọ́. Ẹ ti ya ara yín kúrò lọ́dọ̀ Kristi, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fẹ́ ìdáláre nípa òfin. Ẹ ti yapa kúrò ní ọ̀nà oore-ọ̀fẹ́. Ṣugbọn ní tiwa, nípasẹ̀ Ẹ̀mí ni à ń retí ìdáláre nípa igbagbọ. Nítorí ọ̀ràn pé a kọlà tabi a kò kọlà kò jẹ́ nǹkankan fún àwọn tí ó wà ninu Kristi Jesu. Ohun tí ó ṣe kókó ni igbagbọ tí ó ń ṣiṣẹ́ nípa ìfẹ́. Ẹ ti ń sáré ìje dáradára bọ̀. Ta ni kò jẹ́ kí ẹ gba òtítọ́ mọ́? Ìyípadà ọkàn yín kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun tí ó pè yín. Ìwúkàrà díẹ̀ níí mú kí gbogbo ìyẹ̀fun wú sókè. Mo ní ìdánilójú ninu Oluwa pé ẹ kò ní ní ọkàn mìíràn. Ṣugbọn ẹni tí ó ń yọ yín lẹ́nu yóo gba ìdájọ́ Ọlọrun, ẹni yòówù kí ó jẹ́. Ará, tí ó bá jẹ́ pé iwaasu pé kí eniyan kọlà ni mò ń wà, kí ló dé tí wọ́n fi ń ṣe inúnibíni sí mi? Ǹjẹ́ a ti mú ohun ìkọsẹ̀ agbelebu Kristi kúrò? Ìbá wù mí kí àwọn tí ó ń yọ yín lẹ́nu kúkú gé ara wọn sọnù patapata! Òmìnira ni a pè yín sí, ẹ̀yin ará, ṣugbọn kí ẹ má ṣe lo òmìnira yín fún ìtẹ́lọ́rùn ara yín, ìfẹ́ ni kí ẹ máa fi ran ara yín lọ́wọ́. Nítorí gbolohun kan kó gbogbo òfin já, èyí ni pé “Fẹ́ràn ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ.” Ṣugbọn bí ẹ bá ń bá ara yín jà, tí ẹ̀ ń bu ara yín ṣán, ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà pa ara yín run. Ṣugbọn mò ń sọ fun yín pé kí ẹ jẹ́ kí Ẹ̀mí máa darí ìgbé-ayé yín, tí ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ ẹ kò ní mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara ṣẹ. Nítorí ohun tí ara ń fẹ́ lòdì sí àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí; bẹ́ẹ̀ sì ni ohun tí Ẹ̀mí ń fẹ́ lòdì sí àwọn nǹkan ti ara. Ẹ̀mí ati ara lòdì sí ara wọn. Àyọrísí rẹ̀ ni pé ẹ kì í lè ṣe àwọn ohun tí ó wù yín láti ṣe. Bí Ẹ̀mí bá ń darí yín, ẹ kò sí lábẹ́ òfin. Àwọn iṣẹ́ ara farahàn gbangba. Àwọn ni àgbèrè, ìwà èérí, wọ̀bìà; ìbọ̀rìṣà, oṣó, odì-yíyàn, ìjà, owú-jíjẹ, ìrúnú, ọ̀kánjúwà, ìyapa, rìkíṣí; inú burúkú, ìmutípara, àríyá àwọn ọ̀mùtí ati irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Ohun tí mo ti sọ fun yín tẹ́lẹ̀, ni mo tún ń sọ fun yín, pé àwọn tí ó ń ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò ní jogún ìjọba Ọlọrun. Ṣugbọn èso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, alaafia, sùúrù, àánú, iṣẹ́ rere, ìṣòtítọ́, ìwà pẹ̀lẹ́, ìsẹ́ra-ẹni. Kò sí òfin kan tí ó lòdì sí irú nǹkan báwọ̀nyí. Àwọn tíí ṣe ti Kristi Jesu ti kan àwọn nǹkan ti ara mọ́ agbelebu pẹlu ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ati ìgbádùn ara. Bí a bá wà láàyè nípa Ẹ̀mí, ẹ jẹ́ kí á máa gbé ìgbé-ayé ti Ẹ̀mí. Ẹ má jẹ́ kí á máa ṣe ògo asán, kí á má máa rú ìjà sókè láàrin ara wa, kí á má sì máa jowú ara wa. Ará, bí ẹ bá ká ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ ẹnìkan lọ́wọ́, kí ẹ̀yin tí ẹ̀mí ń darí ìgbé-ayé yín mú irú ẹni bẹ́ẹ̀ bọ̀ sípò pẹlu ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Ṣọ́ra rẹ, kí á má baà dán ìwọ náà wò. Ẹ máa ran ara yín lẹ́rù, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú òfin Kristi ṣẹ. Nítorí bí ẹnìkan bá rò pé òun jẹ́ pataki nígbà tí kò jẹ́ nǹkan, ara rẹ̀ ni ó ń tàn jẹ. Kí olukuluku yẹ iṣẹ́ ara rẹ̀ wò, nígbà náà yóo lè ṣògo lórí iṣẹ́ tirẹ̀, kì í ṣe pé kí ó máa fi iṣẹ́ tirẹ̀ wé ti ẹlòmíràn. Nítorí olukuluku gbọdọ̀ ru ẹrù tirẹ̀. Ẹni tí ó ń kọ́ ẹ̀kọ́ ìyìn rere gbọdọ̀ máa pín olùkọ́ rẹ̀ ninu àwọn nǹkan rere rẹ̀. Ẹ má tan ara yín jẹ: eniyan kò lè mú Ọlọrun lọ́bọ. Ohunkohun tí eniyan bá gbìn ni yóo ká. Nítorí àwọn tí ó bá ń gbin nǹkan ti Ẹ̀mí yóo ká àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí, tíí ṣe ìyè ainipẹkun. Kí á má ṣe jẹ́ kí ó sú wa láti ṣe rere, nítorí nígbà tí ó bá yá, a óo kórè rẹ̀, bí a kò bá jẹ́ kí ó rẹ̀ wá. Nítorí náà, bí a bá ti ń rí ààyè kí á máa ṣe oore fún gbogbo eniyan, pàápàá fún àwọn ìdílé onigbagbọ. Ọwọ́ ara mi ni mo fi kọ ìwé yìí si yín, ẹ wò ó bí ó ti rí gàdàgbà-gadagba! Gbogbo àwọn tí wọn ń fẹ́ kí àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn mọ̀ wọ́n ní ẹni rere ni wọ́n fẹ́ fi ipá mu yín kọlà, kí àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn má baà ṣe inúnibíni sí wọn nítorí agbelebu Kristi. Nítorí àwọn tí wọ́n kọlà pàápàá kì í pa gbogbo òfin mọ́. Ṣugbọn wọ́n fẹ́ kí ẹ kọlà kí wọ́n máa fi yín fọ́nnu pé àwọn mu yín kọlà. Ṣugbọn ní tèmi, kí á má rí i pé mò ń fọ́nnu kiri àfi nítorí agbelebu Oluwa wa Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí ayé yìí ti di ohun tí a kàn mọ́ agbelebu lójú mi, tí èmi náà sì di ẹni tí a kàn mọ́ agbelebu lójú rẹ̀. Nítorí ati a kọlà ni, ati a kò kọlà ni, kò sí èyí tí ó já mọ́ nǹkankan. Ohun tí ó ṣe pataki ni ẹ̀dá titun. Kí alaafia ati àánú Ọlọrun kí ó wà pẹlu gbogbo àwọn tí ó bá ń gbé ìgbé-ayé wọn nípa ìlànà yìí, ati pẹlu àwọn eniyan Ọlọrun. Láti ìgbà yìí lọ, kí ẹnikẹ́ni má ṣe yọ mí lẹ́nu mọ́, nítorí ojú pàṣán wà ní ara mi tí ó fihàn pé ti Jesu ni mí. Ará, kí oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Oluwa wa kí ó wà pẹlu yín. Amin. Èmi Paulu, aposteli Kristi Jesu nípa ìfẹ́ Ọlọrun, ni mò ń kọ ìwé yìí sí àwọn eniyan Ọlọrun tí ó wà ní Efesu, àwọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí Kristi Jesu. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba wa ati Oluwa Jesu Kristi kí ó wà pẹlu yín. Ẹ jẹ́ kí á fi ìyìn fún Ọlọrun Baba Oluwa wa Jesu Kristi, tí ó ti fi ọpọlọpọ ibukun ti ẹ̀mí fún wa lọ́run nípasẹ̀ Kristi. Òun ni ó yàn wá nípasẹ̀ Kristi kí ó tó fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀. Ó yàn wá kí á lè jẹ́ ẹni tí a yà sọ́tọ̀, tí kò ní àléébù níwájú rẹ̀, tí ó sì kún fún ìfẹ́. Ó ti pinnu tẹ́lẹ̀ láti fi wá ṣe ọmọ rẹ̀ nípasẹ̀ Jesu Kristi, ohun tí ó fẹ́ tí inú rẹ̀ sì dùn sí nìyí; kí á lè mọyì ẹ̀bùn rẹ̀ tí ó lógo tí ó fi fún wa lọ́fẹ̀ẹ́ nípasẹ̀ Kristi àyànfẹ́ rẹ̀. Nípasẹ̀ Kristi ni a ti ní ìdáǹdè nítorí ẹ̀jẹ̀ tí ó ta sílẹ̀. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a ti rí ìdáríjì gbà fún àwọn ìrékọjá wa, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀. A ní oore-ọ̀fẹ́ yìí lọpọlọpọ! Ó fún wa ní gbogbo ọgbọ́n ati òye. Ó jẹ́ kí á mọ àṣírí ìfẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ètò tí ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ tí ó ti ṣe ninu Kristi. Èyí ni pé, nígbà tí àkókò bá tó, kí ó lè ṣe ohun gbogbo ní àṣeparí ninu Kristi nígbà tí ó bá yá, ìbáà ṣe àwọn ohun tí ó wà ninu àwọn ọ̀run, tabi àwọn ohun tí ó wà lórí ilẹ̀, kí ó lè sọ wọ́n di ọ̀kan ninu Kristi. Nípasẹ̀ Kristi kan náà ni Ọlọrun ti pín wa ní ogún. Ètò tí ó ti ṣe fún wa nìyí, òun tí ó ń mú ohun gbogbo ṣẹ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀. Àyọrísí gbogbo èyí ni pé kí àwa Juu tí a kọ́kọ́ ní ìrètí ninu Kristi lè yìn ín lógo. Ninu Kristi kan náà ni ẹ̀yin tí kì í ṣe Juu ti gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́, tíí ṣe ìyìn rere ìgbàlà yín tí ẹ gbàgbọ́. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni Ọlọrun ti fi Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó ṣe ìlérí fun yín bí èdìdì. Ẹ̀mí Mímọ́ yìí jẹ́ onídùúró ogún tí a óo gbà nígbà tí Ọlọrun bá dá àwọn eniyan rẹ̀ nídè, kí á lè yin Ọlọrun lógo. Nítorí èyí, láti ìgbà tí mo ti gbọ́ nípa igbagbọ yín ninu Oluwa Jesu, ati ìfẹ́ yín sí gbogbo àwọn onigbagbọ, èmi náà kò sinmi láti máa dúpẹ́ nítorí yín, mo sì ń ranti yín ninu adura mi. Mò ń gbadura pé kí Ọlọrun, Baba Oluwa wa Jesu Kristi, Baba ológo, lè fun yín ní ẹ̀mí ọgbọ́n, kí ó sì jẹ́ kí ẹ ní ìmọ̀ tí ó kún nípa òun alára. Mo sì tún ń gbadura pé kí ó lè là yín lójú ẹ̀mí, kí ẹ lè mọ ìrètí tí ó ní tí ó fi pè yín, kí ẹ sì lè mọ ògo tí ó wà ninu ogún rẹ̀ tí yóo pín fun yín pẹlu àwọn onigbagbọ, ati bí agbára rẹ̀ ti tóbi tó fún àwa tí a gbàgbọ́, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ títóbi agbára rẹ̀. Ó fi agbára yìí hàn ninu Kristi nígbà tí ó jí i dìde ninu òkú, tí ó mú un jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lọ́run. Ó ga ju gbogbo àwọn ọlọ́lá ati aláṣẹ ati àwọn alágbára ati àwọn olóye tí wọ́n wà lójú ọ̀run lọ. Ó tún ga ju gbogbo orúkọ tí eniyan lè dá lọ, kì í ṣe ní ayé yìí nìkan, ṣugbọn ati ní ayé tí ń bọ̀ pẹlu. Ọlọrun ti fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ Kristi yìí kan náà ó fi ṣe orí fún gbogbo ìjọ onigbagbọ. Ìjọ ni ara Kristi, Kristi ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ohun gbogbo. Òun ni ó ń mú ohun gbogbo kún. Nígbà kan rí ẹ jẹ́ òkú ninu ìwàkiwà ati ẹ̀ṣẹ̀ yín. Nígbà náà ẹ̀ ń hùwà gẹ́gẹ́ bí ẹni ti ayé yìí, ẹ̀ ń gbọ́ràn sí aláṣẹ àwọn ẹ̀mí tí ó wà ninu òfuurufú lẹ́nu, àwọn ẹ̀mí wọnyi ń ṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyìí ninu àwọn ọmọ tí kò gbọ́ràn sí Ọlọrun lẹ́nu. Gbogbo àwa yìí náà ti wà lára irú wọn rí, nígbà tí à ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wa, tí à ń ṣe àwọn nǹkan tí ara bá fẹ́ ati àwọn ohun tí ọkàn bá ti rò. Nígbà náà, nípa ti ẹ̀dá ara, àwa náà wà ninu àwọn ọmọ tí Ọlọrun ìbá bínú sí, gẹ́gẹ́ bí àwọn eniyan yòókù. Ṣugbọn nítorí ìfẹ́ ńlá tí Ọlọrun tí ó ní àánú pupọ ní sí wa, ó sọ wá di alààyè pẹlu Kristi nígbà tí a ti di òkú ninu ìwàkíwà wa. Oore-ọ̀fẹ́ ni a fi gbà yín là. Ọlọrun tún jí wa dìde pẹlu Kristi Jesu, ó wá fi wá jókòó pẹlu rẹ̀ lọ́run, kí ó lè fihàn ní àkókò tí ó ń bọ̀ bí ọlá oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ ti tóbi tó, nípa àánú tí ó ní sí wa ninu Kristi Jesu. Nítorí oore-ọ̀fẹ́ ni a fi gbà yín là nípa igbagbọ. Kì í ṣe nítorí iṣẹ́, ẹ̀bùn Ọlọrun ni. Kì í ṣe ìtorí iṣẹ́ tí eniyan ṣe, kí ẹnikẹ́ni má baà máa gbéraga. *** Nítorí òun ni ó dá wa bí a ti rí, ó dá wa fún iṣẹ́ rere nípasẹ̀ Kristi Jesu, àwọn iṣẹ́ tí Ọlọrun ti ṣe tẹ́lẹ̀, pé kí á máa ṣe. Nítorí náà, ẹ ranti pé nígbà kan rí, ẹ jẹ́ abọ̀rìṣà gẹ́gẹ́ bí ipò tí a bi yín sí. Àwọn tí wọ́n kọlà ti ara, tí wọ́n fi ọwọ́ kọ sì ń pè yín ní aláìkọlà. Nígbà náà ẹ wà ní ipò ẹni tí kò mọ Kristi. Ẹ jẹ́ àjèjì sí àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ Israẹli. Àwọn majẹmu tí ó ní ìlérí Ọlọrun ninu sì tún ṣe àjèjì si yín. Ẹ wà ninu ayé láìní ìrètí ati láìní Ọlọrun. Ṣugbọn nisinsinyii, ninu Kristi Jesu, ẹ̀yin tí ẹ wà ní ọ̀nà jíjìn nígbà kan rí, ti súnmọ́ ìtòsí nípa ẹ̀jẹ̀ tí Kristi ta sílẹ̀. Nítorí pé Kristi yìí ni alaafia wa. Òun ni ó sọ àwọn tí wọ́n kọlà ati àwọn tí kò kọlà di ọ̀kan. Nígbà tí ó gbé ara eniyan wọ̀, ó wó ògiri ìkélé tí ó wà láàrin wọn tí wọ́n fi ń yan ara wọn lódì. Ó sọ òfin ati àwọn ìlànà ati àṣẹ di nǹkan yẹpẹrẹ, kí ó lè sọ àwọn mejeeji di ẹ̀dá titun kan náà ninu ara rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú alaafia wá sáàrin wọn. Ó làjà láàrin àwọn mejeeji, ó sọ wọ́n di ara kan lọ́dọ̀ Ọlọrun nípa agbelebu. Ó ti mú odì yíyàn dópin lórí agbelebu. Nígbà tí ó dé, ó waasu ìyìn rere alaafia fún ẹ̀yin tí ẹ wà ní ọ̀nà jíjìn, ó sì waasu ìyìn rere alaafia fún àwọn tí ó wà nítòsí. Nítorí nípasẹ̀ rẹ̀ ni àwa mejeeji ṣe rí ààyè láti dé ọ̀dọ̀ Baba nípa Ẹ̀mí kan náà. Nítorí náà, ẹ kì í tún ṣe àlejò ní ìlú àjèjì mọ́, ṣugbọn ẹ jẹ́ ọmọ-ìbílẹ̀ pẹlu àwọn onigbagbọ, ẹ sì di mọ̀lẹ́bí ninu agbo-ilé Ọlọrun. Lórí àwọn aposteli ati àwọn wolii ni a ti fi ìpìlẹ̀ ìdílé yìí lélẹ̀, Kristi Jesu fúnrarẹ̀ sì ni òkúta igun ilé. Òun ni ó mú kí gbogbo ilé dúró dáradára, tí ó sì mú un dàgbà láti di ilé ìsìn mímọ́ fún Oluwa. Ẹ̀mí ń kọ́ àwa ati ẹ̀yin papọ̀ ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi kí á lè di ibùgbé Ọlọrun. Ìdí rẹ̀ nìyí tí èmi Paulu fi di ẹlẹ́wọ̀n fún Kristi Jesu nítorí ti ẹ̀yin tí ẹ kì í ṣe Juu. Ẹ óo ṣá ti gbọ́ nípa iṣẹ́ tí Ọlọrun fi fún mi nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ láti ṣe fun yín. Ọlọrun ni ó fi àṣírí yìí hàn mí lójú ìran, gẹ́gẹ́ bí mo ti kọ ọ́ sinu ìwé ní ṣókí tẹ́lẹ̀. Nígbà tí ẹ bá kà á, ẹ óo rí i pé mo ní òye àṣírí Kristi, tí Ọlọrun kò fihan àwọn ọmọ eniyan ní ìgbà àtijọ́, ṣugbọn tí ó fihan àwọn aposteli rẹ̀ mímọ́ ati àwọn wolii rẹ̀ nisinsinyii, ninu ẹ̀mí. Àṣírí yìí ni pé àwọn tí kì í ṣe Juu ní anfaani láti pín ninu ogún pẹlu àwọn Juu, ara kan náà sì ni wọ́n pẹlu àwọn tí wọ́n jọ ní ìlérí ninu Kristi Jesu nípasẹ̀ ìyìn rere rẹ̀. Èyí ni iṣẹ́ tí a fi fún mi nípa ẹ̀bùn oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀. Nítorí èmi tí mo kéré jùlọ ninu gbogbo àwọn onigbagbọ ni Ọlọrun fi oore-ọ̀fẹ́ yìí fún, pé kí n máa waasu fún àwọn tí kì í ṣe Juu nípa àwámárìídìí ọrọ̀ Kristi. Ati pé kí n ṣe àlàyé nípa ètò àṣírí yìí, tí Ọlọrun ẹlẹ́dàá ohun gbogbo ti fi pamọ́ láti ìgbà àtijọ́, kí ó lè sọ ọ́ di mímọ̀ ní àkókò yìí láti ọ̀dọ̀ ìjọ, kí ó sì lè fihan àwọn alágbára ati àwọn aláṣẹ tí ó wà ninu àwọn ọ̀run bí ọgbọ́n Ọlọrun ti pọ̀ tó ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà. Ọlọrun ṣe èyí gẹ́gẹ́ bí ètò rẹ̀, láti ayérayé, tí ó mú ṣẹ ninu Kristi Jesu Oluwa wa. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a fi ní ìgboyà láti dé ọ̀dọ̀ Ọlọrun. A sì ní ìdánilójú pé a ti rí ààyè dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ nípa igbagbọ. Nítorí èyí, mò ń gbadura pé kí ọkàn yín má ṣe rẹ̀wẹ̀sì nítorí ìpọ́njú tí mò ń rí nítorí yín. Ohun ìṣògo ni èyí jẹ́ fun yín. Nítorí èyí ni mo ṣe ń fi ìkúnlẹ̀ gbadura sí Baba, tí à ń fi orúkọ rẹ̀ pe gbogbo ìdílé lọ́run ati láyé. Mò ń gbadura pé, gẹ́gẹ́ bíi títóbi ògo rẹ̀, kí ó fun yín ní agbára Ẹ̀mí rẹ̀ tí yóo fún ọkàn yín ní okun; kí Kristi fi ọkàn yín ṣe ilé nípa igbagbọ kí ẹ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ninu ìfẹ́, kí ìpìlẹ̀ ìgbé-ayé yín jẹ́ ti ìfẹ́, kí ẹ lè ní agbára, pẹlu gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun, láti mọ bí ìfẹ́ Kristi ti gbòòrò tó, bí ó ti gùn tó, bí ó ti ga tó, ati bí ó ti jìn tó; kí ẹ lè mọ bí ìfẹ́ Kristi ti tayọ ìmọ̀ ẹ̀dá tó, kí ẹ sì lè kún fún gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọrun. Ògo ni fún ẹni tí ó lè ṣe ju gbogbo nǹkan tí à ń bèèrè, ati ohun gbogbo tí a ní lọ́kàn lọ, gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ tí ń ṣiṣẹ́ ninu wa. Kí ògo yìí wà fún un ninu ìjọ ati ninu Kristi Jesu láti ìrandíran títí laelae. Amin. Nítorí náà, èmi tí mo di ẹlẹ́wọ̀n nítorí ti Oluwa, ń bẹ̀ yín pé kí ẹ máa hùwà gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, bí irú ìpè tí Ọlọrun pè yín. Kí ẹ máa hùwà pẹlu ìrẹ̀lẹ̀ ati ọkàn tútù, kí ẹ sì máa mú sùúrù. Kí ẹ máa fi ìfẹ́ bá ara yín lò nípa ìfaradà. Ẹ ní ìtara láti pa ìṣọ̀kan ti Ẹ̀mí mọ́ ninu alaafia tí ó so yín pọ̀. Ara kan ni ó wà, ati Ẹ̀mí kan, gẹ́gẹ́ bí ìpè tí a ti pè yín ti jẹ́ ti ìrètí kan. Oluwa kan ṣoṣo ni ó wà, ati igbagbọ kan, ati ìrìbọmi kan. Ọlọrun kan ni ó wà, tíí ṣe Baba gbogbo eniyan, òun ni olórí ohun gbogbo, tí ó ń ṣiṣẹ́ ninu ohun gbogbo, tí ó sì wà ninu ohun gbogbo. Ṣugbọn ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ti rí oore-ọ̀fẹ́ gbà gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ẹ̀bùn tí Kristi fi fún wa. Nítorí èyí ni Ìwé Mímọ́ ṣe sọ pé, “Nígbà tí ó lọ sí òkè ọ̀run, ó kó àwọn ìgbèkùn lẹ́yìn, ó sì fi ẹ̀bùn fún àwọn eniyan.” Nígbà tí ó sọ pé, “Ó lọ sí òkè ọ̀run,” ìtumọ̀ èyí kò lè yéni tóbẹ́ẹ̀ bí kò bá jẹ́ pé ó ti kọ́kọ́ wá sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀. Òun kan náà tí ó wá sí ìsàlẹ̀ ni ó lọ sí òkè, tí ó tayọ gbogbo nǹkan tí ó wà lọ́run, kí ó lè sọ gbogbo nǹkan di kíkún. Ó fún àwọn ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn láti jẹ́ aposteli, àwọn ẹlòmíràn, láti jẹ́ wolii, àwọn ẹlòmíràn, láti jẹ́ ajíyìnrere, àwọn ẹlòmíràn, láti jẹ́ alufaa ati olùkọ́ni. Àwọn ẹ̀bùn wọnyi wà fún lílò láti mú kí ara àwọn eniyan Ọlọrun lè dá ṣáṣá kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ iranṣẹ, ati láti mú kí ara Kristi lè dàgbà. Báyìí ni gbogbo wa yóo fi dé ìṣọ̀kan ninu igbagbọ ati ìmọ̀ Ọmọ Ọlọrun, tí a óo fi di géńdé, tí a óo fi dàgbà bí Kristi ti dàgbà. A kì í tún ṣe ọmọ-ọwọ́ mọ́, tí ìgbì yóo máa bì sọ́tùn-ún, sósì, tabi tí afẹ́fẹ́ oríṣìíríṣìí ẹ̀kọ́ àrékérekè àwọn tí wọn ń lo ọgbọ́n-ẹ̀wẹ́ láti fi tan eniyan jẹ yóo máa fẹ́ káàkiri. Ṣugbọn a óo máa sọ òtítọ́ pẹlu ìfẹ́, a óo máa dàgbà ninu rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà, ninu Kristi tíí ṣe orí. Òun ni ó mú kí gbogbo ẹ̀yà ara wà ní ìṣọ̀kan, tí gbogbo oríkèé-ríkèé ara wa sì wà ní ipò wọn, pẹlu iṣan tí ó mú wọn dúró, tí gbogbo wọn sì ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ipò olukuluku wọn, tí gbogbo ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan fi ń dàgbà, tí ó ń mú kí gbogbo ara rẹ̀ dàgbà ninu ìfẹ́. Nítorí náà, mò ń sọ fun yín, mo sì ń bẹ̀ yín ní orúkọ Oluwa pé, kí ẹ má máa hùwà bíi ti àwọn abọ̀rìṣà mọ́, àwọn tí wọn ń hùwà gẹ́gẹ́ bí èrò asán ọkàn wọn. Ọkàn àwọn yìí ti ṣókùnkùn, ó sì ti yàtọ̀ pupọ sí irú ìgbé-ayé tí Ọlọrun fẹ́. Nítorí òpè ni wọ́n, ọkàn wọn ti le. Wọn kò bìkítà: wọ́n ti fi ara wọn fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara nípa oríṣìíríṣìí ìwà burúkú nítorí ojúkòkòrò. Ṣugbọn a kò kọ́ ẹ̀yin bẹ́ẹ̀ nípa Kristi. Ẹ ti gbọ́ nípa Jesu, a sì ti fi òtítọ́ rẹ̀ kọ yín, pé kí ẹ jìnnà sí irú ìwà àtijọ́ tí ẹ ti ń hù, ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara tíí máa tan eniyan lọ sinu ìparun. Kí Ẹ̀mí Mímọ́ sọ yín di ẹni titun ninu ọkàn yín. Kí ẹ wá gbé ẹni titun nnì tí Ọlọrun dá wọ̀, kí ẹ lè máa ṣe òdodo, kí ẹ sì máa hu ìwà mímọ́ ninu òtítọ́. Nítorí náà, ẹ fi èké ṣíṣe sílẹ̀. Kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín máa bá ẹnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́, nítorí gbogbo wa jẹ́ ẹ̀yà ara kan náà. Bí ẹ bá bínú, ẹ má jẹ́ kí ibinu mu yín dẹ́ṣẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ ba yín ninu ibinu. Ẹ má fi ààyè gba Èṣù. Kí ẹni tí ń jalè má jalè mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀ kí ó kúkú gbìyànjú láti fi ọwọ́ ara rẹ̀ ṣe iṣẹ́ rere, kí òun náà lè ní ohun tí yóo fún àwọn aláìní. Ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ kankan kò gbọdọ̀ ti ẹnu yín jáde. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ rere, tí ó lè jẹ́ ìrànlọ́wọ́ nígbàkúùgbà ni kí ẹ máa sọ jáde lẹ́nu. Èyí yóo ṣe àwọn tí ó bá gbọ́ ní anfaani. Ẹ má kó ìbànújẹ́ bá Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọrun, tí Ọlọrun fi ṣèdìdì yín títí di ọjọ́ ìràpadà. Ẹ níláti mú gbogbo inú burúkú, ìrúnú, ibinu, ariwo ati ìsọkúsọ kúrò láàrin yín ati gbogbo nǹkan burúkú. Ẹ máa ṣoore fún ara yín, ẹ ní ojú àánú; kí ẹ sì máa dáríjì ara yín, gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti dáríjì yín nípasẹ̀ Kristi. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí àyànfẹ́ ọmọ, ẹ fi ìwà jọ Ọlọrun. Ẹ máa rìn ninu ìfẹ́ gẹ́gẹ́ bí Kristi ti fẹ́ wa, tí ó fi ara òun tìkararẹ̀ rú ẹbọ olóòórùn dídùn sí Ọlọrun nítorí tiwa. Kí á má ṣe gbúròó ìwà àgbèrè, tabi oríṣìíríṣìí ìṣekúṣe, tabi ojúkòkòrò láàrin àwọn eniyan Ọlọrun. Ìwà ìtìjú, ọ̀rọ̀ òmùgọ̀, tabi àwàdà burúkú kò yẹ yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọpẹ́ sí Ọlọrun ni ó yẹ yín. Ẹ̀yin alára mọ̀ dájú pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ó ń ṣe àgbèrè, tabi tí ó ń ṣe ìṣekúṣe, tabi tí ó ní ojúkòkòrò, tabi tí ó ń bọ̀rìṣà, tí yóo ní ìpín ninu ìjọba Kristi, tíí ṣe ìjọba Ọlọrun. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fi ọ̀rọ̀ asán tàn yín jẹ. Nítorí irú èyí ni ibinu Ọlọrun fi ń bọ̀ wá sórí àwọn ọmọ aláìgbọràn. Nítorí náà ẹ má ṣe fi ara wé wọn. Nítorí nígbà kan, ninu òkùnkùn patapata ni ẹ wà. Ṣugbọn ní àkókò yìí ẹ ti bọ́ sinu ìmọ́lẹ̀ nítorí ẹ ti di ẹni Oluwa. Ẹ máa hùwà bí ọmọ ìmọ́lẹ̀. Nítorí èso ìmọ́lẹ̀ ni oríṣìíríṣìí iṣẹ́ rere, òdodo ati òtítọ́. Kí ẹ máa wádìí ohun tí yóo wu Oluwa. Ẹ má ṣe bá àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ òkùnkùn tí kò léso rere kẹ́gbẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa bá wọn wí. Nítorí àwọn ohun tí wọn ń ṣe níkọ̀kọ̀ tilẹ̀ ti eniyan lójú láti sọ. Nítorí gbogbo nǹkan tí ìmọ́lẹ̀ bá tàn sí níí máa hàn kedere. Ohun gbogbo tí ó bá hàn kedere di ìmọ́lẹ̀. Bí ọ̀rọ̀ orin kan ti sọ, pé, “Dìde, ìwọ tí ò ń sùn; jí dìde kúrò ninu òkú, Kristi yóo tan ìmọ́lẹ̀ sí ọ lára.” Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra bí ẹ ti ń hùwà. Ẹ má ṣe hùwà bí ẹni tí kò gbọ́n, ṣugbọn ẹ hùwà bí ọlọ́gbọ́n. Ẹ lo gbogbo àkókò yín dáradára nítorí àkókò tí a wà yìí burú. Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ aṣiwèrè, ṣugbọn kí ẹ máa fi òye gbé ohun tíí ṣe ìfẹ́ Oluwa. Ẹ má máa mu ọtí yó, òfò ni. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ máa fi Orin Dafidi ati orin ìyìn ati orin àtọkànwá bá ara yín sọ̀rọ̀. Ẹ máa kọrin; ẹ máa fi ìyìn fún Oluwa ninu ọ̀kan yín. Ẹ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun Baba nígbà gbogbo fún gbogbo nǹkan ní orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi. Ẹ máa tẹríba fún ara yín nítorí ọ̀wọ̀ tí ẹ̀ ń bù fún Kristi. Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín gẹ́gẹ́ bí Oluwa. Nítorí ọkọ ni olórí aya gẹ́gẹ́ bí Kristi ti jẹ́ olórí ìjọ. Kristi sì ni Olùgbàlà ara rẹ̀ tíí ṣe ìjọ. Bí ìjọ ti ń bọ̀wọ̀ fún Kristi, bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn aya máa ṣe sí àwọn ọkọ wọn ninu ohun gbogbo. Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fẹ́ràn àwọn aya yín, gẹ́gẹ́ bí Kristi ti fẹ́ràn ìjọ, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún un. Ó ṣe èyí láti yà á sọ́tọ̀. Ó sọ ọ́ di mímọ́ lẹ́yìn tí ó ti fi omi wẹ̀ ẹ́ nípa ọ̀rọ̀ iwaasu. Kí ó lè mú ìjọ wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ bí ìjọ tí ó lọ́lá, tí kò ní àléébù kankan, tabi kí ó hunjọ, tabi kí ó ní nǹkan àbùkù kankan, ṣugbọn kí ó lè jẹ́ ìjọ mímọ́ tí kò ní èérí. Bẹ́ẹ̀ ni ó yẹ kí àwọn ọkọ fẹ́ràn àwọn aya wọn, bí wọ́n ti fẹ́ràn ara tiwọn. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn aya rẹ̀, òun tìkararẹ̀ ni ó fẹ́ràn. Nítorí kò sí ẹnìkan tí ó kórìíra ara rẹ̀. Ńṣe ni eniyan máa ń tọ́jú ara rẹ̀, tí ó sì máa ń kẹ́ ẹ. Bẹ́ẹ̀ ni Kristi ń ṣe sí ìjọ. Nítorí ẹ̀yà ara Kristi ni a jẹ́. Gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti sọ, pé, “Nítorí náà ni ọkunrin yóo ṣe fi baba ati ìyá rẹ̀ sílẹ̀, tí yóo darapọ̀ pẹlu aya rẹ̀, àwọn mejeeji yóo wá di ara kan.” Àṣírí ńlá ni èyí. Mò ń sọ nípa ipò tí Kristi wà sí ìjọ. Àkàwé yìí ba yín mu. Ẹnìkọ̀ọ̀kan yín níláti fẹ́ràn aya rẹ̀ bí òun tìkararẹ̀. Aya sì níláti bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀. Ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbọ́ ti àwọn òbí yín nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni ó dára. “Bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ.” Èyí níí ṣe òfin kinni pẹlu ìlérí, pé “Kí ó lè dára fún ọ, ati kí o lè pẹ́ lórí ilẹ̀ náà.” Ẹ̀yin òbí, ẹ má ṣe mú àwọn ọmọ yín bínú. Títọ́ ni kí ẹ máa tọ́ wọn ninu ẹ̀kọ́ ati ìlànà ti onigbagbọ. Ẹ̀yin ẹrú, ẹ máa gbọ́ ti àwọn tí wọ́n jẹ́ oluwa yín nípa ti ara, pẹlu ọ̀wọ̀ ati ìbẹ̀rù, pẹlu ọkàn kan gẹ́gẹ́ bí ẹni pé Kristi ni ẹ̀ ń ṣe é fún. Kí ó má ṣe jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá ń ṣọ́ yín nìkan ni ẹ óo máa ṣiṣẹ́ bí ìgbà tí ẹ fẹ́ gba ìyìn eniyan. Ṣugbọn bí ẹrú Kristi, ẹ máa ṣe ìfẹ́ Ọlọrun láti ọkàn wá. Ẹ máa ṣe iṣẹ́ yín pẹlu inú dídùn, bí ẹni pé fún Oluwa, kì í ṣe fún eniyan. Nítorí ẹ mọ̀ pé ohun rere tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín bá ṣe, olúwarẹ̀ ìbáà jẹ́ ẹrú tabi kí ó jẹ́ òmìnira, yóo rí èrè gbà lọ́dọ̀ Oluwa. Ẹ̀yin ọ̀gá, bákan náà ni kí ẹ máa ṣe sí àwọn ẹrú yín. Ẹ má máa dẹ́rù bà wọ́n. Ẹ ranti pé ati àwọn, ati ẹ̀yin, ẹ ní Oluwa kan lọ́run, tí kì í ṣe ojuṣaaju. Ní ìparí, ẹ jẹ́ alágbára ninu Oluwa, kí ẹ fi agbára rẹ̀ ṣe okun yín. Ẹ gbé gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ̀, kí ẹ lè dúró láti dojú kọ èṣù pẹlu ọgbọ́n àrékérekè rẹ̀. Nítorí kì í ṣe eniyan ni à ń bá jagun, bíkòṣe àwọn ẹ̀mí burúkú ojú ọ̀run, àwọn aláṣẹ ati àwọn alágbára òkùnkùn ayé yìí. Nítorí èyí, ẹ gbé gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ̀, kí ẹ lè dìde dúró láti jà nígbà tí ọjọ́ ibi bá dé. Nígbà tí ìjà bá sì dópin, kí ẹ lè wà ní ìdúró. Nítorí náà, ẹ dúró gbọningbọnin. Ẹ fi òtítọ́ ṣe ọ̀já ìgbànú yín. Ẹ fi òdodo bo àyà yín bí apata. Ẹ jẹ́ kí ìmúrasílẹ̀ láti waasu ìyìn rere alaafia jẹ́ bàtà ẹsẹ̀ yín. Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọnyi, ẹ fi igbagbọ ṣe ààbò yín. Nípa rẹ̀ ni ẹ óo lè fi pa iná gbogbo ọfà amúbíiná tí èṣù ń ta. Ẹ fi ìgbàlà ṣe fìlà onírin tí ẹ óo máa dé, kí ẹ sì mú idà Ẹ̀mí Mímọ́, tíí ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ẹ máa gbadura nígbà gbogbo, kí ẹ máa fi gbogbo ẹ̀bẹ̀ yín siwaju Ọlọrun nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Nítorí náà, ẹ máa gbadura láì sùn, láì wo, fún gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun. Ẹ máa gbadura fún èmi gan-an alára, pé kí n lè mọ ohun tí ó yẹ kí n sọ nígbà tí n óo bá sọ̀rọ̀. Ati pé kí n lè fi ìgboyà sọ̀rọ̀ tí àwọn eniyan yóo fi mọ àṣírí ìyìn rere tí mo jẹ́ ikọ̀ fún, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè mí. Ẹ gbadura pé kí n lè fi ìgboyà sọ̀rọ̀ bí ó ti yẹ. Kí ẹ lè mọ bí nǹkan ti ń lọ sí lọ́dọ̀ mi, ati ohun tí mò ń ṣe, Tukikọsi yóo sọ gbogbo rẹ̀ fun yín. Àyànfẹ́ arakunrin ni, ati iranṣẹ tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ninu iṣẹ́ Oluwa. Ìdí tí mo fi rán an si yín ni pé kí ẹ lè mọ bí gbogbo nǹkan ti ń lọ sí lọ́dọ̀ wa, kí ọkàn yín lè balẹ̀. Kí alaafia ati ìfẹ́ pẹlu igbagbọ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba ati Oluwa Jesu Kristi, kí ó wà pẹlu àwọn onigbagbọ. Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹlu gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn Oluwa wa, Jesu Kristi pẹlu ìfẹ́ tí kò lópin. Èmi Paulu ati Timoti, àwa iranṣẹ Kristi Jesu. À ń kọ ìwé yìí sí gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun tí ó wà ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi Jesu, tí wọ́n wà ní Filipi pẹlu gbogbo àwọn alabojuto ati àwọn olùrànlọ́wọ́ wọn. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba wa ati Oluwa wa Jesu Kristi kí ó wà pẹlu yín. Nígbà gbogbo tí mo bá ranti yín ni mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun mi. Nígbà gbogbo ni mò ń gbadura fún gbogbo yín pẹlu ayọ̀ ninu ọkàn mi. Nítorí láti ìbẹ̀rẹ̀ títí di àkókò yìí ni ẹ ti ń bá mi ṣiṣẹ́ pọ̀ ninu iṣẹ́ ìyìn rere. Ó dá mi lójú pé ẹni tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere ninu yín yóo ṣe é dé òpin títí di ọjọ́ tí Kristi Jesu yóo dé. Ẹ̀tọ́ ni fún mi láti ní irú èrò yìí nípa gbogbo yín, nítorí mo kó ọ̀rọ̀ yín lékàn. Nítorí pé nígbà tí mo wà ninu ẹ̀wọ̀n ati ìgbà tí mo ní anfaani láti gbèjà ara mi ati láti fi ìdí ọ̀rọ̀ ìyìn rere múlẹ̀, gbogbo yín ni ẹ jẹ́ alájọpín oore-ọ̀fẹ́ Kristi pẹlu mi. Mo fi Ọlọrun ṣe ẹ̀rí pé àárò gbogbo yín ń sọ mí, pẹlu ọkàn ìyọ́nú ti Kristi Jesu. Adura mi ni pé kí ìfẹ́ yín máa gbòòrò sí i, kí ìmọ̀ yín máa pọ̀ sí i, kí ẹ túbọ̀ máa ní làákàyè sí i, kí ẹ lè mọ àwọn ohun tí ó dára jùlọ. Kí ẹ lè jẹ́ aláìlábùkù, kí ẹ sì wà láìsí ohun ìkùnà kan ní ọjọ́ tí Kristi bá dé. Mo tún gbadura pé kí ẹ lè kún fún èso iṣẹ́ òdodo tí ó ti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi wá fún ògo ati ìyìn Ọlọrun. Ẹ̀yin ará, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí mi mú kí iṣẹ́ ìyìn rere túbọ̀ tàn kalẹ̀ ni. Ó ti wá hàn sí gbogbo àwọn tí ó wà ní ààfin ati gbogbo àwọn eniyan yòókù pé nítorí ti Kristi ni mo ṣe wà ninu ẹ̀wọ̀n. Èyí fún ọpọlọpọ ninu àwọn onigbagbọ tí wọ́n mọ ìdí tí mo fi wà ninu ẹ̀wọ̀n ní ìgboyà gidigidi láti máa waasu ìyìn rere láì bẹ̀rù. Àwọn ẹlòmíràn ń waasu Kristi nítorí owú ati nítorí pé wọ́n fẹ́ràn asọ̀. Àwọn ẹlòmíràn sì wà tí wọn ń waasu Kristi pẹlu inú rere. Àwọn kan ń fi ìfẹ́ waasu Kristi nítorí wọ́n mọ̀ pé nítorí ti ọ̀rọ̀ ìyìn rere ni wọ́n ṣe sọ mí sẹ́wọ̀n. Àwọn kan ń sọ̀rọ̀ Kristi nítorí ohun tí wọn óo rí gbà níbẹ̀, kì í ṣe pẹlu inú kan, wọ́n rò pé àwọn lè mú kí ìrora mi ninu ẹ̀wọ̀n pọ̀ sí i. Kí ni àyọrísí gbogbo èyí? Lọ́nà kan tabi lọ́nà mìíràn, ìbáà ṣe pẹlu ẹ̀tàn ni, tabi pẹlu òtítọ́ inú, a sá ń waasu Kristi, èyí ni ó mú inú mi dùn. Inú mi yóo sì máa dùn ni, nítorí mo mọ̀ pé àyọrísí rẹ̀ ni pé a óo dá mi sílẹ̀ nípa adura yín ati nípa àtìlẹ́yìn Ẹ̀mí Jesu Kristi, gẹ́gẹ́ bí igbẹkẹle ati ìrètí mi pé n kò ní rí ohun ìtìjú kan. Ṣugbọn bí mo ti máa ń gbé Kristi ga ninu ara mi pẹlu ìgboyà nígbà gbogbo, bẹ́ẹ̀ gan-an náà ni n óo tún máa gbé e ga nisinsinyii ìbáà jẹ́ pé mo wà láàyè tabi pé mo kú. Nítorí pé Kristi ni mo wà láàyè fún ní tèmi, bí mo bá sì kú, èrè ni ó jẹ́. Bí mo bá wà láàyè ninu ẹran-ara, iṣẹ́ tí ó lérè ni ó jẹ́ fún mi. N kò tilẹ̀ mọ èyí tí ǹ bá yàn. Ọkàn mi ń ṣe meji; ọkàn mi kan fẹ́ pé kí á dá mi sílẹ̀, kí n lọ sọ́dọ̀ Jesu, nítorí èyí ni ó dára jùlọ. Ṣugbọn ó tún ṣàǹfààní bí mo bá wà láàyè ninu ẹran-ara, nítorí tiyín. Èyí dá mi lójú, nítorí náà mo mọ̀ pé n óo wà láàyè. Bí mo bá wà ní ọ̀dọ̀ gbogbo yín, yóo mú ìlọsíwájú ati ayọ̀ ninu igbagbọ wá fun yín. Èyí yóo mú kí ìṣògo yín ninu Kristi Jesu lè pọ̀ sí i nítorí mi, nígbà tí mo bá tún yọ si yín. Nǹkankan tí ó ṣe pataki ni pé kí ẹ jẹ́ kí ìwà yín kí ó jẹ́ irú èyí tí ó bá ìyìn rere Kristi mu, tí ó jẹ́ pé bí mo bá wá tí mo ri yín, tabi bí n kò bá lè wá ṣugbọn tí mò ń gbúròó yín, kí n gbọ́ pé ẹ wà pọ̀ ninu ẹ̀mí kan ati ọkàn kan, ati pé gbogbo yín ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹlu igbagbọ ninu iṣẹ́ ìyìn rere. Ẹ má jẹ́ kí ẹ̀rù àwọn alátakò bà yín rárá ninu ohunkohun. Èyí ni yóo jẹ́ ẹ̀rí ìparun wọn, yóo sì jẹ́ ẹ̀rí ìgbàlà yín. Ọlọrun ni yóo ṣe é. Nítorí anfaani ni èyí fun yín, kì í ṣe pé kí ẹ gba Kristi gbọ́ nìkan ni, ṣugbọn pé ẹ̀ ń jìyà fún Kristi. Irú ìyà kan náà tí ẹ rí ninu ìgbé-ayé mi, tí ẹ tún ń gbọ́ pé mò ń jẹ títí di àkókò yìí ni ẹ̀yin náà ń jẹ báyìí. Nítorí náà, bí ẹ bá ní ìwúrí kankan ninu Kristi, bí ìfẹ́ rẹ̀ bá fun yín ní ìtùnú, bí ẹ bá ní ìrẹ́pọ̀ ninu Ẹ̀mí, bí ẹ bá ní ojú àánú, ẹ mú kí ayọ̀ mi kún nípa pé kí ọkàn yín ṣe ọ̀kan, kí ẹ fẹ́ nǹkankan náà, kí ẹ ní inú kan, kí èrò yín sì papọ̀. Ẹ má ṣe ohunkohun pẹlu ẹ̀mí àṣehàn tabi láti gba ìyìn eniyan, ṣugbọn pẹlu ọkàn ìrẹ̀lẹ̀, ẹ máa fi ẹnìkejì yín ṣiwaju ara yín. Ẹ má máa mójútó nǹkan ti ara yín nìkan, ṣugbọn ẹ máa mójútó nǹkan àwọn ẹlòmíràn náà. Ẹ máa ní èrò yìí ninu ara yín, irú èyí tí ó wà ninu Kristi Jesu, ẹni tí ó wá ní àwòrán Ọlọrun, sibẹ kò ka ipò jíjẹ́ ọ̀kan pẹlu Ọlọrun sí ohun tí ìbá gbé léjú. Ṣugbọn ó bọ́ ògo rẹ̀ sílẹ̀, ó gbé àwòrán ẹrú wọ̀, ó wá farahàn ní àwọ̀ eniyan. Ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó gbọ́ràn sí Ọlọrun lẹ́nu títí dé ojú ikú, àní ikú lórí agbelebu. Nítorí náà ni Ọlọrun ṣe gbé e ga ju ẹnikẹ́ni lọ; ó sì fún un ní orúkọ tí ó ga ju gbogbo orúkọ yòókù lọ, pé ní orúkọ Jesu ni gbogbo ẹ̀dá yóo máa wólẹ̀, lọ́run ati láyé, ati nísàlẹ̀ ilẹ̀; gbogbo ẹ̀dá yóo sì máa jẹ́wọ́ pé, “Jesu Kristi ni Oluwa,” fún ògo Ọlọrun Baba. Nítorí náà, ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń gbọ́ràn nígbà gbogbo, tí kì í ṣe nígbà tí mo bá wà lọ́dọ̀ yín nìkan, ṣugbọn pàápàá jùlọ ní àkókò yìí tí n kò sí lọ́dọ̀ yín, ẹ máa ṣe iṣẹ́ ìgbàlà yín pẹlu ìbẹ̀rù ati ìwárìrì. Nítorí pé Ọlọrun ní ń fun yín ní agbára, láti fẹ́ ṣe ìfẹ́ rẹ̀, ati láti lè ṣe ohun tí ó wù ú. Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú tabi iyàn jíjà, kí ẹ lè jẹ́ Ọmọ Ọlọrun, tí kò lẹ́bi tí kò sì ní àléébù, ọmọ Ọlọrun tí ó pé, láàrin àwọn ìran tí ọ̀nà wọn wọ́, tí ìwà wọn sì ti bàjẹ́. Láàrin irú àwọn eniyan wọnyi ni ẹ̀ ń tàn bí ìmọ́lẹ̀ ninu ayé, tí ẹ sì ń polongo ọ̀rọ̀ ìyè. Èyí ni yóo jẹ́ ìṣògo fún mi ní ọjọ́ tí Kristi bá dé, nítorí yóo hàn pé iré-ìje tí mò ń sá kì í ṣe lásán, ati pé aápọn tí mo ti ṣe kò já sí òfo. Ṣugbọn bí a bá fi mí ṣe ohun ìrúbọ ati ohun èèlò ninu ìsìn nítorí igbagbọ yín, ó dùn mọ́ mi, n óo sì máa yọ̀ pẹlu gbogbo yín. Nítorí náà, kí inú yín kí ó máa dùn, kí ẹ sì máa bá mi yọ̀. Lágbára Oluwa, mò ń gbèrò ati rán Timoti si yín láì pẹ́, kí n lè ní ìwúrí nígbà tí mo bá gbúròó yín. N kò ní ẹlòmíràn tí ó dàbí rẹ̀ tí ọkàn wa rí bákan náà, tí ó sì tún ń fi tìfẹ́tìfẹ́ ṣe àwọn nǹkan tí ó bá jẹ mọ́ tiyín. Nítorí nǹkan ti ara wọn ni gbogbo àwọn yòókù ń wá, wọn kò wá nǹkan ti Jesu Kristi. Ṣugbọn ẹ mọ bí Timoti ti wúlò tó, nítorí bí ọmọ tíí ṣe pẹlu baba rẹ̀ ni ó ń ṣe iṣẹ́ iranṣẹ pẹlu mi ninu iṣẹ́ ìyìn rere. Nítorí náà, òun ni mo lérò pé n óo rán nígbà tí mo bá mọ bí ọ̀rọ̀ mi yóo ti já sí. Ṣugbọn mo ní igbẹkẹle ninu Oluwa pé èmi fúnra mi yóo wá láìpẹ́. Mo kà á sí pé ó di dandan pé kí n rán Epafiroditu pada si yín. Ó jẹ́ arakunrin mi, alábàáṣiṣẹ́ pẹlu mi, ati ọmọ-ogun pẹlu mi. Ó tún jẹ́ òjíṣẹ́ ati aṣojú yín tí ó ń mójútó àìní mi. Nítorí ọkàn gbogbo yín ń fà á, ọkàn rẹ̀ kò sì balẹ̀ nítorí gbígbọ́ tí ẹ ti gbọ́ pé ó ṣàìsàn. Òtítọ́ ni, ó ṣàìsàn, ó tilẹ̀ fẹ́rẹ̀ kú! Ṣugbọn Ọlọrun ṣàánú rẹ̀, kì í sìí ṣe òun nìkan ni, Ọlọrun ṣàánú èmi náà, kí n má baà ní ìbànújẹ́ kún ìbànújẹ́. Nítorí náà, ní wéréwéré yìí ni mò ń rán an bọ̀ kí ẹ lè tún rí i, kí inú yín lè dùn, kí ọkàn tèmi náà sì lè balẹ̀. Kí ẹ gbà á tọwọ́-tẹsẹ̀ ninu Oluwa, kí ẹ máa bu ọlá fún irú àwọn bẹ́ẹ̀. Nítorí pé ó fẹ́rẹ̀ kú nítorí iṣẹ́ Kristi. Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu, kí ó lè rọ́pò yín ninu ohun tí ó kù tí ó yẹ kí ẹ ṣe gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ fún mi. Ní gbolohun kan, ẹ̀yin ará mi, ẹ máa yọ̀ ninu Oluwa. Kò ṣòro fún mi láti kọ àwọn nǹkankan náà si yín, ó tilẹ̀ dára bẹ́ẹ̀ fun yín. Ẹ ṣọ́ra fún àwọn ajá. Ẹ ṣọ́ra fún àwọn oníṣẹ́ burúkú. Ẹ ṣọ́ra fún àwọn ọ̀kọlà! Nítorí àwa gan-an ni ọ̀kọlà, àwa tí à ń sin Ọlọrun nípa Ẹ̀mí, tí à ń ṣògo ninu Kristi Jesu, tí a kò gbára lé nǹkan ti ara, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti gbára lé nǹkan ti ara nígbà kan rí. Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ní ìdí láti fi gbára lé nǹkan ti ara, mo ní i ju ẹnikẹ́ni lọ. Ní ọjọ́ kẹjọ ni wọ́n kọ mí nílà. Ọmọ Israẹli ni mí, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, Heberu paraku ni mí. Nípa ti Òfin Mose, Farisi ni mí. Ní ti ìtara ninu ẹ̀sìn, mo ṣe inúnibíni sí ìjọ Kristi. Ní ti òdodo nípa iṣẹ́ Òfin, n kò kùnà níbìkan. Ṣugbọn ohunkohun tí ó ti jẹ́ èrè fún mi ni mo kà sí àdánù. Mo ka gbogbo nǹkan wọnyi sí àdánù nítorí ohun tí ó ṣe iyebíye jùlọ, èyí ni láti mọ Kristi Jesu Oluwa mi, nítorí ẹni tí mo fi pàdánù ohun gbogbo, tí mo fi kà wọ́n sí ìgbẹ́, kí n lè jèrè Jesu. Ati pé kí á lè rí i pé mo wà ninu Jesu ati pé n kò ní òdodo ti ara mi nípa iṣẹ́ Òfin bíkòṣe òdodo nípa igbagbọ. Gbogbo àníyàn ọkàn mi ni pé kí n mọ Kristi ati agbára ajinde rẹ̀, kí èmi náà jẹ ninu irú ìyà tí ó jẹ, kí n sì dàbí rẹ̀ nípa ikú rẹ̀, bí ó bá ṣeéṣe kí n lè dé ipò ajinde ninu òkú. Kì í ṣe pé ọwọ́ mi ti bà á ná, tabi pé mo ti di pípé. Ṣugbọn mò ń lépa ohun tí Kristi ti yàn mí fún. Ẹ̀yin ará, èmi gan-an kò ka ara mi sí ẹni tí ó ti dé ibi tí mò ń lọ. Ṣugbọn nǹkankan ni, èmi a máa gbàgbé ohun gbogbo tí ó ti kọjá, èmi a sì máa nàgà láti mú ohun tí ó wà níwájú. Mò ń làkàkà láti dé òpin iré-ìje mi tíí ṣe èrè ìpè láti òkè wá: ìpè Ọlọrun ninu Kristi Jesu. Nítorí náà, gbogbo àwa tí a ti dàgbà ninu ẹ̀sìn kí á máa ní irú èrò yìí. Bí ẹnikẹ́ni bá wá ní èrò tí ó yàtọ̀ sí èyí, Ọlọrun yóo fihàn yín. Ṣugbọn bí a ti ń ṣe bọ̀ nípa ìwà ati ìṣe, bẹ́ẹ̀ ni kí á ṣe máa tẹ̀síwájú. Ẹ̀yin ará, gbogbo yín ẹ máa fara wé mi, kí ẹ máa ṣàkíyèsí àwọn tí ń hùwà gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí a ti jẹ́ fun yín. Nítorí ọpọlọpọ ń hùwà bí ọ̀tá agbelebu Kristi. Bí mo ti ń sọ fun yín tẹ́lẹ̀ nígbàkúùgbà, bẹ́ẹ̀ ni mo tún ń fi omijé sọ nisinsinyii. Ìparun ni ìgbẹ̀yìn wọn. Ikùn wọn ni ọlọrun wọn. Ohun ìtìjú ni wọ́n fi ń ṣe ìgbéraga. Afẹ́-ayé ni wọ́n gbé lékàn. Nítorí pé ní tiwa, ọ̀run ni ìlú wa wà, níbi tí a ti ń retí Olùgbàlà, Oluwa Jesu Kristi, ẹni tí yóo tún ara ìrẹ̀lẹ̀ wa ṣe kí ó lè dàbí ara tirẹ̀ tí ó lógo, gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ tí ó fi lè fi ohun gbogbo sí ìkáwọ́ ara rẹ̀. Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi, àyànfẹ́, tí ọkàn mi ń fà sí, ayọ̀ mi, ati adé mi, ẹ dúró gbọningbọnin ninu Oluwa. Mo bẹ Yuodia ati Sintike pé kí wọ́n bá ara wọn rẹ́ nítorí ti Oluwa. Bẹ́ẹ̀ ni mo bẹ ìwọ náà, ẹlẹgbẹ́ mi tòótọ́, ran àwọn obinrin wọnyi lọ́wọ́, nítorí wọ́n ti bá mi ṣiṣẹ́ pọ̀ ninu iṣẹ́ ìtànkálẹ̀ ìyìn rere pẹlu Kilẹmẹnti ati gbogbo olùbáṣiṣẹ́ mi yòókù, àwọn tí orúkọ wọn wà ninu ìwé ìyè. Ẹ máa yọ̀ ninu Oluwa nígbà gbogbo. Mo tún wí: ẹ máa yọ̀. Ẹ jẹ́ kí ó hàn sí gbogbo eniyan pé ẹ ní ẹ̀mí ìfaradà. Oluwa fẹ́rẹ̀ dé! Ẹ má ṣe jẹ́ kí ohunkohun dààmú yín, ṣugbọn ninu gbogbo adura ati ẹ̀bẹ̀ yín, ẹ máa fi àwọn ìbéèrè yín siwaju Ọlọrun pẹlu ọpẹ́. Alaafia Ọlọrun, tí ó tayọ òye eniyan yóo pa ọkàn ati èrò yín mọ́ ninu Kristi Jesu. Ní ìparí, ẹ̀yin ará, gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe òtítọ́, gbogbo nǹkan tí ó bá lọ́lá, gbogbo nǹkan tí ó bá tọ́, gbogbo nǹkan tí ó bá jẹ́ mímọ́, gbogbo nǹkan tí ó bá fa eniyan mọ́ra, gbogbo nǹkan tí ó bá ní ìròyìn rere, àwọn ni kí ẹ máa kó lé ọkàn. Àwọn ohun tí ẹ ti kọ́ lọ́dọ̀ mi, tí ẹ bá lọ́wọ́ mi, tí ẹ ti gbọ́ lẹ́nu mi, tí ẹ ti rí ninu ìwà mi, àwọn ni kí ẹ máa ṣe. Ọlọrun alaafia yóo sì wà pẹlu yín. Mo láyọ̀ pupọ ninu Oluwa nítorí ọ̀rọ̀ mi tún ti bẹ̀rẹ̀ sí sọjí ninu èrò yín. Kò sí ìgbà kan tí ẹ kì í ronú nípa mi ṣugbọn ẹ kò rí ààyè láti ṣe àwọn ohun tí ẹ̀ ń gbèrò. N kò sọ èyí nítorí mo ṣe aláìní, nítorí mo ti kọ́ láti máa ní ìtẹ́lọ́rùn ní ipòkípò tí mo bá wà. Mo mọ bí eniyan ti ń gbé ìgbé-ayé ninu àìní, mo sì mọ bí eniyan ti ń gbé ìgbé-ayé ninu ọpọlọpọ ọrọ̀. Nípòkípò tí mo bá wà, ninu ohun gbogbo, mo ti kọ́ àṣírí bí a ti ń ní ìtẹ́lọ́rùn, kì báà jẹ́ ninu ebi tabi ayo, ninu ọ̀pọ̀ tabi àìní. Mo lè ṣe ohun gbogbo ninu Kristi ẹni tí ó ń fún mi ní agbára. Sibẹ ẹ ṣeun tí ẹ bá mi pín ninu ìpọ́njú mi. Ẹ̀yin ará Filipi mọ̀ pé ní ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìyìn rere mi, nígbà tí mo kúrò ní Masedonia, kò sí ìjọ kan tí ó bá mi lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ fífúnni lẹ́bùn ati gbígba ẹ̀bùn jọ fúnni àfi ẹ̀yin nìkan ṣoṣo. Nítorí nígbà tí mo wà ní Tẹsalonika kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan mọ, ó tó ẹẹmeji tí ẹ fi nǹkan ranṣẹ sí mi. Kì í ṣe ẹ̀bùn ni mò ń wá, ṣugbọn mò ń wá ọpọlọpọ èso fún anfaani yín. Ìwé ẹ̀rí nìyí fún ohun gbogbo tí ẹ fún mi, ó tilẹ̀ ti pọ̀jù. Mo ní ànító nígbà tí mo rí ohun tí ẹ fi rán Epafiroditu sí mi gbà. Ó dàbí òróró olóòórùn dídùn, bí ẹbọ tí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà, tí inú Ọlọrun dùn sí. Ọlọrun mi yóo pèsè fún gbogbo àìní ẹ̀yin náà, gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ ọrọ̀ rẹ̀ tí ó lógo nípasẹ̀ Jesu Kristi. Kí ògo kí ó jẹ́ ti Ọlọrun Baba wa lae ati laelae. Amin. Ẹ kí gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun tí ó jẹ́ ti Kristi Jesu. Àwọn arakunrin tí ó wà lọ́dọ̀ mi ki yín. Gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun ki yín, pàápàá jùlọ àwọn ti ìdílé Kesari. Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa Jesu Kristi kí ó wà pẹlu ẹ̀mí yín. Èmi Paulu, aposteli Kristi Jesu, nípa ìfẹ́ Ọlọrun, ati Timoti arakunrin wa, àwa ni à ń kọ ìwé yìí— Sí ìjọ eniyan Ọlọrun tí ó wà ní Kolose, sí àwọn arakunrin tí ó jẹ́ olóòótọ́ sí Kristi. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba wa kí ó wà pẹlu yín. À ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, Baba Oluwa wa, Jesu Kristi, nígbà gbogbo tí a bá ń gbadura fun yín. A ti gbúròó igbagbọ yín ninu Kristi Jesu ati ìfẹ́ tí ẹ ní sí gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun. Ìrètí tí ó wà fun yín ni ọ̀run, tí ẹ gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ òtítọ́ ìyìn rere, ni orísun igbagbọ ati ìfẹ́ yín. Ìyìn rere yìí ti dé ọ̀dọ̀ yín gẹ́gẹ́ bí ó ti dé ọ̀dọ̀ gbogbo aráyé, ó ń so èso, ó sì ń dàgbà. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí láàrin ẹ̀yin náà láti ọjọ́ tí ẹ ti gbọ́, tí ẹ sì ti mọ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun nítòótọ́. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ ti kọ́ ọ̀rọ̀ ìyìn rere lọ́dọ̀ Epafirasi, àyànfẹ́, alábàáṣiṣẹ́pọ̀ wa. Òun ni ó sọ fún wa nípa ìfẹ́ yín ninu nǹkan ti ẹ̀mí. Nítorí náà, láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ ìròyìn yín, àwa náà kò sinmi láti máa gbadura fun yín. À ń bẹ̀bẹ̀ pé kí Ọlọrun lè jẹ́ kí ẹ mọ ìfẹ́ rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ pẹlu gbogbo ọgbọ́n, kí ó sì fun yín ní òye nípa nǹkan ti ẹ̀mí. A tún ń gbadura pé kí ìgbé-ayé yín lè jẹ́ èyí tí ó wu Oluwa lọ́nà gbogbo, kí iṣẹ́ rere yín máa pọ̀ sí i, kí ẹ máa tẹ̀síwájú ninu ìmọ̀ Ọlọrun. Ati pé kí Ọlọrun fun yín ní agbára gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ògo rẹ̀, kí ó fun yín ní ìfaradà ninu ohun gbogbo, pẹlu sùúrù ati ayọ̀. Kí ẹ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Baba wa tí ó kà yín yẹ láti ní ìpín ninu ogún àwọn eniyan Ọlọrun ninu ìmọ́lẹ̀. *** Baba wa náà ni ó gbà wá lọ́wọ́ agbára òkùnkùn, ó sì mú wa wá sinu ìjọba àyànfẹ́ Ọmọ rẹ̀. Nípasẹ̀ ọmọ rẹ̀ yìí ni a fi ní ìdáǹdè, àní ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wa. Eniyan kò lè rí Ọlọrun, ṣugbọn ọmọ yìí ni àwòrán rẹ̀, òun ni àkọ́bí ohun gbogbo tí a dá. Nítorí pé, nípasẹ̀ rẹ̀ ni a ti dá ohun gbogbo, lọ́run ati láyé: ati ohun tí a rí, ati ohun tí a kò rí, ìbáà ṣe ìtẹ́ ọba, tabi ìjọba, tabi àwọn alágbára, tabi àwọn aláṣẹ. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a ti dá gbogbo nǹkan, nítorí tirẹ̀ ni a sì ṣe dá wọn. Ó ti wà ṣiwaju ohun gbogbo. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni gbogbo nǹkan sì fi wà létò. Òun ni orí fún ara, tíí ṣe ìjọ. Òun ni ìbẹ̀rẹ̀, àkọ́bí tí a jí dìde láti inú òkú, kí ó lè wà ní ipò tí ó ga ju gbogbo nǹkan lọ. Nítorí ó wu Ọlọrun pé kí ohun tí Ọlọrun tìkararẹ̀ jẹ́ máa gbé inú rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Nípa rẹ̀ ni Ọlọrun ṣe gbogbo nǹkan lọ́kan pẹlu ara rẹ̀, kí alaafia lè dé nípa ikú rẹ̀ lórí agbelebu. Gbogbo nǹkan wá wà ní ìṣọ̀kan, ìbáà ṣe nǹkan ti ayé tabi àwọn nǹkan ti ọ̀run. Ẹ̀yin tí ẹ ti jẹ́ àlejò ati ọ̀tá ninu ọkàn yín nípa iṣẹ́ burúkú yín ni Ọlọrun wá mú wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu ara rẹ̀ nípa ikú ọmọ rẹ̀, kí ó lè sọ yín di ẹni tí ó mọ́, tí kò ní àbùkù, tí kò sì ní ẹ̀sùn níwájú rẹ̀, tí ẹ bá dúró ninu igbagbọ, tí ẹ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀, tí ẹ dúró gbọningbọnin, tí ẹ kò kúrò ninu ìrètí ìyìn rere tí ẹ ti gbọ́, tí èmi Paulu jẹ́ iranṣẹ rẹ̀, tí a ti waasu rẹ̀ fún gbogbo ẹ̀dá ayé. Ní àkókò yìí, mo láyọ̀ ninu ìyà tí mò ń jẹ nítorí yín. Ìyà tí mò ń jẹ ninu ara mi yìí ni èyí tí ó kù tí Kristi ìbá jẹ fún ìjọ, tíí ṣe ara rẹ̀. Nítorí èyí ni mo ṣe di iranṣẹ láti mú ọ̀rọ̀ Ọlọrun ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tí Ọlọrun ti fún mi láti ṣe nítorí yín. Ìjìnlẹ̀ àṣírí nìyí, ó ti wà ní ìpamọ́ láti ìgbà àtijọ́ ati láti ìrandíran, ṣugbọn Ọlọrun fihan àwọn eniyan rẹ̀ ní àkókò yìí. Àwọn ni ó wu Ọlọrun pé kí wọ́n mọ ọlá ati ògo àṣírí yìí láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu. Àṣírí náà ni pé, Kristi tí ó ń gbé inú yín ni ìrètí ògo. Kristi yìí ni à ń kéde fun yín, tí à ń kìlọ̀ rẹ̀ fún gbogbo eniyan, tí a fi ń kọ́ gbogbo eniyan ní gbogbo ọgbọ́n, kí á lè sọ gbogbo eniyan di pípé ninu Kristi. Ohun tí mò ń ṣiṣẹ́ fún nìyí gẹ́gẹ́ bí agbára tí Ọlọrun fún mi, tí ó ń fún mi ní okun. Nítorí mo fẹ́ kí ẹ mọ bí mo ti ń ṣe akitiyan tó nítorí yín ati nítorí àwọn tí ó wà ní Laodikia ati nítorí àwọn tí kò mọ̀ mí sójú. Ìdí akitiyan mi ni pé kí Ọlọrun lè mu yín ní ọkàn le, kí ó so yín pọ̀ ninu ìfẹ́ ati ọrọ̀ òye tí ó dájú, kí ẹ sì ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àṣírí Ọlọrun, tíí ṣe Kristi fúnrarẹ̀. Ninu Kristi ni Ọlọrun fi gbogbo ìṣúra ọgbọ́n ati ìmọ̀ pamọ́ sí. Mò ń sọ èyí kí ẹnikẹ́ni má baà fi ọ̀rọ̀ dídùn tàn yín jẹ. Nítorí bí n kò tilẹ̀ sí lọ́dọ̀ yín nípa ti ara, sibẹ mo wà pẹlu yín ninu ẹ̀mí. Mo láyọ̀ nígbà tí mo rí ètò tí ó wà láàrin yín ati bí igbagbọ yín ti dúró ninu Kristi. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gba Kristi Jesu bí Oluwa, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ máa gbé ìgbé-ayé yín ni ìrẹ́pọ̀ pẹlu rẹ̀. Kí ẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀, kí ẹ máa dàgbà ninu rẹ̀, kí ẹ sì jẹ́ kí igbagbọ yín dúró ṣinṣin bí ẹ ti kọ́ láti ṣe, kí ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo. Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má ṣe fi ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ayé ati ìtànjẹ lásán sọ yín di ẹrú gẹ́gẹ́ bí àṣà eniyan, ati ìlànà àwọn ẹ̀mí tí a kò fi ojú rí, tí ó yàtọ̀ sí ètò ti Kristi. Nítorí pé ninu Kristi tí ó jẹ́ eniyan ni ohun tí Ọlọrun fúnrarẹ̀ jẹ́, ń gbé lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Ó sì ti ṣe yín ní pípé ninu rẹ̀. Òun níí ṣe orí fún gbogbo àwọn ẹ̀mí ojú ọ̀run, ìbáà ṣe ìjọba tabi àwọn aláṣẹ. Ninu Kristi yìí ni a ti kọ yín nílà, kì í ṣe ilà tí a fi ọwọ́ kọ nípa gígé ẹran-ara kúrò, ṣugbọn ilà ti Kristi; nígbà tí a sin yín ninu omi ìrìbọmi, tí ẹ tún jinde nípa igbagbọ pẹlu agbára Ọlọrun tí ó jí Kristi dìde ninu òkú. Ẹ̀yin tí ẹ ti di òkú nípa ẹ̀ṣẹ̀ yín, tí ẹ jẹ́ aláìkọlà nípa ti ara, ni Ọlọrun ti sọ di alààyè pẹlu Kristi. Ọlọrun ti dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. Ó ti pa àkọsílẹ̀ tí ó lòdì sí wa rẹ́, ó mú un kúrò, ó kàn án mọ́ agbelebu. Ó gba agbára lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí ojú ọ̀run: ati ìjọba ni, ati àwọn alágbára wọ̀n-ọn-nì; ó bọ́ wọn síhòòhò, ó fi wọ́n ṣẹ̀sín ní gbangba, nígbà tí ó ti ṣẹgun wọn lórí agbelebu. Nítorí náà ẹ má gbà fún ẹnikẹ́ni kí ó máa darí yín nípa nǹkan jíjẹ tabi nǹkan mímu, tabi nípa ọ̀rọ̀ àjọ̀dún tabi ti oṣù titun tabi ti Ọjọ́ Ìsinmi. Àwọn nǹkan wọnyi jẹ́ àwòjíìjí ohun tí ó ń bọ̀, ṣugbọn nǹkan ti Kristi ni ó ṣe pataki. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni da yín lẹ́bi, kí ó sọ fun yín pé kí ẹ máa fi ìyà jẹ ara yín, kí ẹ máa sin àwọn angẹli. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ ń ṣe ìgbéraga nípa ìran tí ó ti rí, ó ń gbéraga lásán nípa nǹkan ti ara rẹ̀; kò dì mọ́ ẹni tíí ṣe orí, tí ó mú kí gbogbo ara, ati iṣan, ati ẹran-ara wà pọ̀, tí ó ń mú un dàgbà bí Ọlọrun ti fẹ́. Bí ẹ bá ti kú pẹlu Kristi sí àwọn ìlànà ti ẹ̀mí tí a kò rí, kí ló dé tí ẹ fi tún ń pa oríṣìíríṣìí èèwọ̀ mọ́? “Má fọwọ́ kan èyí,” “Má jẹ tọ̀hún,” “Má ṣegbá, má ṣàwo?” Gbogbo àwọn nǹkan wọnyi yóo ṣègbé bí ẹ bá ti lò wọ́n tán. Ìlànà ati ẹ̀kọ́ eniyan ni wọ́n. Ó lè dàbí ẹni pé ọgbọ́n wà ninu àwọn nǹkan wọnyi fún ìsìn ti òde ara ati fún ìjẹra-ẹni-níyà ati fún ìkóra-ẹni-níjàánu. Ṣugbọn wọn kò ṣe anfaani rárá láti jẹ́ kí eniyan borí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara. Nítorí náà, bí a bá ti ji yín dìde pẹlu Kristi, ẹ máa lépa àwọn ohun tí ó wà lọ́run níbi tí Kristi wà, tí ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun. Ẹ máa lépa àwọn ohun tí ó wà lọ́run, ẹ má lépa àwọn ohun tí ó wà láyé. Nítorí ẹ ti kú, ẹ̀mí yín wà ní ìpamọ́ pẹlu Kristi ninu Ọlọrun. Nígbà tí Kristi, ẹni tíí ṣe ẹ̀mí yín bá farahàn, ẹ̀yin náà yóo farahàn pẹlu rẹ̀ ninu ògo. Nítorí náà, ẹ pa àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀yà ara yín ti ayé run: àwọn bíi àgbèrè, ìwà èérí, ìṣekúṣe, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ati ojúkòkòrò tíí ṣe ìbọ̀rìṣà. Nítorí nǹkan wọnyi ni ibinu Ọlọrun ṣe ń bọ̀. Ẹ̀yin náà ti wà lára irú àwọn eniyan wọnyi nígbà kan rí, nígbà tí ẹ̀yin náà ń ṣe nǹkan wọnyi. Ṣugbọn ní àkókò yìí, ẹ pa gbogbo àwọn nǹkan wọnyi tì: ibinu, inúfùfù, ìwà burúkú, ìsọkúsọ, ọ̀rọ̀ ìtìjú. Ẹ má purọ́ fún ara yín, nígbà tí ẹ ti bọ́ ara àtijọ́ sílẹ̀ pẹlu iṣẹ́ rẹ̀, tí ẹ ti gbé ẹ̀dá titun wọ̀. Èyí ni ẹ̀dá tí ó túbọ̀ ń di titun siwaju ati siwaju gẹ́gẹ́ bí àwòrán ẹni tí ó dá a, tí ó ń mú kí eniyan ní ìmọ̀ Ọlọrun. Ninu ipò titun yìí, kò sí pé ẹnìkan ni Giriki, ẹnìkan ni Juu; tabi pé ẹnìkan kọlà, ẹnìkan kò kọlà, ẹnìkan aláìgbédè, ẹnìkan ẹlẹ́nu òdì, ẹnìkan ẹrú, ẹnìkan òmìnira. Nítorí Kristi ni ohun gbogbo, tí ó wà ninu ohun gbogbo. Nítorí náà, ẹ gbé àánú wọ̀ bí ẹ̀wù, ati inú rere, ìrẹ̀lẹ̀, ìwà pẹ̀lẹ́ ati sùúrù, bí ó ti yẹ àwọn ẹni tí Ọlọrun yàn, tí wọ́n sì jẹ́ eniyan Ọlọrun ati àyànfẹ́ rẹ̀. Ẹ ní ìfaradà láàrin ara yín. Ẹ máa dáríjì ara yín bí ẹnikẹ́ni bá ní ẹ̀sùn kan sí ẹnìkejì rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí Oluwa ti dáríjì yín bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe sí ara yín. Boríborí gbogbo nǹkan wọnyi, ni pé kí ẹ gbé ìfẹ́ wọ̀. Ìfẹ́ ni ó so àwọn nǹkan yòókù pọ̀, tí ó sì mú wọn pé. Kí alaafia láti ọ̀dọ̀ Kristi máa ṣe alákòóso ọkàn yín; nítorí Ọlọrun pè yín láti jẹ́ ara kan nítorí alaafia yìí, ẹ sì máa ṣọpẹ́. Kí ọ̀rọ̀ Kristi máa gbé inú yín lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Kí ẹ máa fi gbogbo ọgbọ́n kọ́ ara yín, kí ẹ máa fún ara yín ní ìwúrí nípa kíkọ Orin Dafidi, ati orin ìyìn ati orin àtọkànwá. Ẹ máa kọrin sí Ọlọrun pẹlu ọpẹ́ ninu ọkàn yín. Ohun gbogbo tí ẹ bá ń ṣe, ìbáà jẹ́ pé ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ ni tabi pé ẹ̀ ń ṣe nǹkankan ni, ẹ máa ṣe é ní orúkọ Oluwa Jesu. Ẹ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun Baba nípasẹ̀ rẹ̀. Ẹ̀yin aya, ẹ máa bọ̀wọ̀ fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ kí onigbagbọ máa ṣe. Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fẹ́ràn àwọn aya yín. Ẹ má ṣe kanra mọ́ wọn. Ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn òbí yín lẹ́nu ninu ohun gbogbo, nítorí ohun tí ó wu Oluwa nìyí. Ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe rorò mọ́ àwọn ọmọ yín, kí ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn má baà bá wọn. Ẹ̀yin ẹrú, ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn olówó yín lẹ́nu ninu ohun gbogbo. Kí ó má jẹ́ pé nígbà tí wọn bá ń ṣọ́ yín nìkan ni ẹ óo máa ṣiṣẹ́, bí ìgbà tí ó jẹ́ pé eniyan ni ẹ̀ ń fẹ́ tẹ́ lọ́rùn. Ṣugbọn ẹ fi gbogbo ara ṣiṣẹ́, ní ìbẹ̀rù Oluwa. Ohunkohun tí ẹ bá ń ṣe, ẹ ṣe é tọkàntọkàn, bí ẹni pé Oluwa ni ẹ̀ ń ṣe é fún, kì í ṣe fún eniyan, níwọ̀n ìgbà tí ẹ mọ̀ pé ẹ óo rí ogún gbà gẹ́gẹ́ bí èrè láti ọ̀dọ̀ Oluwa. Oluwa Kristi ni ẹ̀ ń ṣe iṣẹ́ ẹrú fún. Nítorí ẹni tí ó bá ń ṣe àìdára, yóo gba èrè àìdára. Kò ní sí ojuṣaaju. Ẹ̀yin ọ̀gá, ohun tí ó dára ati ohun tí ó yẹ ni kí ẹ máa ṣe sí àwọn ẹrú yín. Kí ẹ ranti pé ẹ̀yin náà ní Ọ̀gá kan ní ọ̀run. Ẹ tẹra mọ́ adura gbígbà. Ẹ máa fi ọkàn bá adura yín lọ. Kí ẹ sì máa dúpẹ́. Ẹ tún máa gbadura fún wa, pé kí Ọlọrun lè ṣí ìlẹ̀kùn iwaasu fún wa, kí á lè sọ ìjìnlẹ̀ àṣírí Kristi. Nítorí èyí ni mo fi wà ninu ẹ̀wọ̀n. Kí ẹ gbadura pé kí n lè ṣe àlàyé bí ó ti yẹ. Ẹ máa gbé ìgbé-ayé yín pẹlu ọgbọ́n níwájú àwọn alaigbagbọ. Ẹ má ṣe jẹ́ kí àkókò kan kọjá láìjẹ́ pé ẹ lò ó bí ó ti yẹ. Ọ̀rọ̀ ọmọlúwàbí ni kí ó máa ti ẹnu yín jáde nígbà gbogbo, ọ̀rọ̀ tí ó bá etí mu, kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ láti dá ẹnikẹ́ni tí ẹ bá ń bá sọ̀rọ̀ lóhùn. Tukikọsi, àyànfẹ́ ati arakunrin wa, yóo fun yín ní ìròyìn nípa mi. Iranṣẹ tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ni ati ẹrú bí àwa náà ninu iṣẹ́ Oluwa. Nítorí èyí gan-an ni mo fi rán an wá sọ́dọ̀ yín, kí ẹ lè mọ bí gbogbo nǹkan ti ń lọ fún wa, kí ó lè fi ọkàn yín balẹ̀. Mo tún rán Onisimu, ọ̀kan ninu yín, tí òun náà jẹ́ àyànfẹ́ ati arakunrin tí ó sì ṣe é gbẹ́kẹ̀lé. Gbogbo bí nǹkan bá ti rí níhìn-ín ni wọn óo ròyìn fun yín. Arisitakọsi, ẹlẹ́wọ̀n, ẹlẹgbẹ́ mi ki yín, ati Maku, ìbátan Banaba. Ẹ ti rí ìwé gbà nípa rẹ̀. Tí ó bá dé ọ̀dọ̀ yín, kí ẹ gbà á tọwọ́-tẹsẹ̀. Jesu tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Jusitu náà ki yín. Àwọn yìí nìkan ni wọ́n kọlà ninu àwọn alábàáṣiṣẹ́ mi ninu iṣẹ́ ìjọba Ọlọrun. Ìtùnú ni wọ́n jẹ́ fún mi. Epafirasi, iranṣẹ Kristi Jesu, ọ̀kan ninu yín, ki yín. Nígbà gbogbo ni ó ń gbadura kíkankíkan fun yín, pé kí ẹ lè dúró ní pípé ati pé kí ẹ lè kún fún gbogbo ohun tíí ṣe ìfẹ́ Ọlọrun. Nítorí pé mo jẹ́rìí rẹ̀ pé ó ti ṣiṣẹ́ pupọ fun yín ati fún àwọn tí ó wà ní Laodikia ati ní Hierapoli. Luku, àyànfẹ́ oníṣègùn ati Demasi ki yín. Ẹ kí àwọn arakunrin tí ó wà ní Laodikia. Ẹ kí Nimfa ati ìjọ tí ó wà ní ilé rẹ̀. Nígbà tí ẹ bá ti ka ìwé yìí tán, kí ẹ rí i pé ìjọ tí ó wà ní Laodikia kà á pẹlu. Kí ẹ̀yin náà sì ka ìwé tí a kọ sí àwọn ará Laodikia. Ẹ sọ fún Akipu pé kí ó má jáfara nípa iṣẹ́ tí ó gbà láti ọ̀dọ̀ Oluwa, kí ó ṣe é parí. Ìkíni tí èmi Paulu fi ọwọ́ ara mi kọ nìyí. Ẹ ranti pé ninu ẹ̀wọ̀n ni mo wà. Kí oore-ọ̀fẹ́ kí ó wà pẹlu yín. Èmi Paulu, ati Silifanu, ati Timoti, ni à ń kọ ìwé yìí sí ìjọ Tẹsalonika, tíí ṣe ìjọ Ọlọrun Baba ati ti Jesu Kristi Oluwa. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia máa wà pẹlu yín. À ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nígbà gbogbo nítorí gbogbo yín, a sì ń ranti yín ninu adura wa nígbà gbogbo. Ninu adura wa sí Ọlọrun Baba wa, à ń ranti bí igbagbọ yín ti ń mú kí ẹ ṣiṣẹ́, tí ìfẹ́ yín ń jẹ́ kí ẹ ṣe akitiyan, tí ìrètí tí ẹ ní ninu Oluwa wa Jesu Kristi sì ń mú kí ẹ ní ìfaradà. Ẹ̀yin ará, àyànfẹ́ Ọlọrun, a mọ̀ pé Ọlọrun ni ó yàn yín. Nígbà tí a mú ìyìn rere wá sí ọ̀dọ̀ yín, a kò mú un wá pẹlu ọ̀rọ̀ ẹnu nìkan; ṣugbọn pẹlu agbára ninu Ẹ̀mí Mímọ́ ni, ati pẹlu ọpọlọpọ ẹ̀rí tí ó dáni lójú. Ẹ̀yin náà kúkú ti mọ irú ẹni tí a jẹ́ nítorí tiyín nígbà tí a wà láàrin yín. Ẹ̀yin náà wá ń fara wé wa, ẹ sì ń fara wé Oluwa. Láàrin ọpọlọpọ inúnibíni ẹ gba ọ̀rọ̀ ìyìn rere tayọ̀tayọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ wá di àpẹẹrẹ fún gbogbo àwọn onigbagbọ tí ó wà ní Masedonia ati Akaya. Nítorí ẹ̀yin ni ẹ tan ìyìn rere ọ̀rọ̀ Oluwa káàkiri, kì í ṣe ní Masedonia ati Akaya nìkan, ṣugbọn níbi gbogbo ni ìròyìn igbagbọ yín sí Ọlọrun ti tàn dé. Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ tún ní pé à ń sọ ohunkohun mọ́. Nítorí wọ́n ń sọ bí ẹ ti ṣe gbà wá nígbà tí a dé ọ̀dọ̀ yín, ati bí ẹ ti ṣe yipada kúrò ninu ìbọ̀rìṣà, láti máa sin Ọlọrun tòótọ́ tíí ṣe Ọlọrun alààyè; ati bí ẹ ti ń retí Jesu, Ọmọ rẹ̀, láti ọ̀run wá, ẹni tí a jí dìde ninu òkú, tí ó yọ wá kúrò ninu ibinu tí ń bọ̀. Ará, ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ pé wíwá tí a wá sọ́dọ̀ yín kì í ṣe lásán. Gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀, lẹ́yìn tí a ti jìyà, tí a ti rí ẹ̀gbin ní Filipi, ni a fi ìgboyà nípa Ọlọrun wá tí a sọ̀rọ̀ ìyìn rere Ọlọrun fun yín láàrin ọpọlọpọ àtakò. Nítorí pé ọ̀rọ̀ ìyànjú wa kì í ṣe ohun ìṣìnà, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ohun èérí tabi ti ìtànjẹ. Ṣugbọn gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti kà wá yẹ, tí ó fi iṣẹ́ ìyìn rere lé wa lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni à ń sọ̀rọ̀, kì í ṣe láti tẹ́ eniyan lọ́rùn, bíkòṣe pé láti tẹ́ Ọlọrun tí ó mọ ọkàn wa lọ́rùn. Nítorí, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀, a kò wá pọ́n ẹnikẹ́ni, a kò sì wá ṣe àṣehàn bí ẹni tí ìwọ̀ra wà lọ́kàn rẹ̀. A fi Ọlọrun ṣe ẹlẹ́rìí! Bẹ́ẹ̀ ni a kò wá ìyìn eniyan, ìbáà ṣe láti ọ̀dọ̀ yín, tabi láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a wà ní ipò láti gba ìyìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Kristi. Ṣugbọn à ń ṣe jẹ́jẹ́ láàrin yín, àní gẹ́gẹ́ bí obinrin alágbàtọ́ tíí ṣe ìtọ́jú àwọn ọmọ tí ó ń tọ́jú. Bẹ́ẹ̀ ni ọkàn wa fà sọ́dọ̀ yín; kì í ṣe ìyìn rere nìkan ni a fẹ́ fun yín, ṣugbọn ó dàbí ẹni pé kí á gbé gbogbo ara wa fun yín, nítorí ẹ ṣọ̀wọ́n fún wa. Ará, ẹ ranti ìṣòro ati làálàá wa, pé tọ̀sán-tòru ni à ń ṣiṣẹ́ láti gbọ́ bùkátà ara wa, kí á má baà ni ẹnikẹ́ni ninu yín lára nígbà tí à ń waasu ìyìn rere Ọlọrun fun yín. Ẹ̀yin gan-an lè jẹ́rìí, Ọlọrun náà sì tó ẹlẹ́rìí wa pé, pẹlu ìwà mímọ́ ati òdodo ati àìlẹ́gàn ni a fi wà láàrin ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́; gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀ pé bí baba ti rí sí àwọn ọmọ rẹ̀ ni a rí sí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín; tí à ń gbà yín níyànjú, tí à ń rọ̀ yín, tí à ń kìlọ̀ fun yín nípa bí ó ti yẹ kí ẹ máa gbé ìgbé-ayé yín bí ẹni tí Ọlọrun pè sinu ìjọba ati ògo rẹ̀. Nítorí náà, àwa náà ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nígbà gbogbo, nítorí nígbà tí ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí ẹ gbọ́ lẹ́nu wa, ẹ gbà á bí ó ti rí gan-an ni. Bí ọ̀rọ̀ Ọlọrun ni ẹ gbà á, kì í ṣe bí ọ̀rọ̀ eniyan. Ọ̀rọ̀ náà sì ń ṣiṣẹ́ ninu ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́. Nítorí, ẹ ti di aláfarawé àwọn ìjọ Ọlọrun tí ó wà ninu Kristi Jesu ní ilẹ̀ Judia, nítorí irú ìyà tí wọ́n jẹ lọ́wọ́ àwọn Juu ni ẹ̀yin náà jẹ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀yà tiyín. Àwọn Juu yìí ni wọ́n pa Oluwa Jesu ati àwọn wolii, tí wọ́n sì fi inúnibíni lé wa jáde. Wọn kò ṣe ohun tí ó wu Ọlọrun, wọ́n sì ń lòdì sí àwọn ohun tí ó lè ṣe eniyan ní anfaani. Wọ́n ń ṣe ìdínà fún wa kí á má baà lè waasu fún àwọn tí kì í ṣe Juu, kí wọn má baà rí ìgbàlà, kí òṣùnwọ̀n ẹ̀ṣẹ̀ wọn baà lè kún. Ṣugbọn ibinu Ọlọrun ti dé sórí wọn. Ẹ̀yin ará, nígbà tí a kúrò lọ́dọ̀ yín fún ìgbà díẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a pínyà nípa ti ara, sibẹ ọkàn wa kò kúrò lọ́dọ̀ yín, ọkàn yín tún ń fà wá gan-an ni. A fẹ́ wá sọ́dọ̀ yín. Kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹ̀ẹ̀kan tabi ẹẹmeji ni èmi Paulu ti fẹ́ wá, ṣugbọn Satani dí wa lọ́wọ́. Nítorí tí kò bá ṣe ẹ̀yin, ta tún ni ìrètí wa, ayọ̀ wa, ati adé tí a óo máa fi ṣògo níwájú Oluwa wa Jesu nígbà tí ó bá farahàn? Ẹ̀yin ni ògo wa ati ayọ̀ wa. Nítorí náà, nígbà tí ara wa kò gbà á mọ́, a pinnu pé kí ó kúkú ku àwa nìkan ní Atẹni; ni a bá rán Timoti si yín, ẹni tí ó jẹ́ arakunrin wa ati alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun ninu iṣẹ́ ìyìn rere ti Kristi, kí ó lè máa gbà yín níyànjú, kí igbagbọ yín lè dúró gbọnin-gbọnin. Kí ẹnikẹ́ni má baà tàn yín jẹ ní àkókò inúnibíni yìí. Nítorí ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ pé onigbagbọ níláti rí irú ìrírí yìí. Nítorí nígbà tí a wà lọ́dọ̀ yín, a ti sọ fun yín tẹ́lẹ̀ pé a níláti jìyà. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí, bí ẹ̀yin náà ti mọ̀. Nítorí náà, èmi náà kò lè fi ara dà á mọ́, ni mo bá ranṣẹ láti wá wádìí nípa ìdúró yín, kí ó má baà jẹ́ pé olùdánwò ti dán yín wò, kí akitiyan wa má baà já sí òfo. Ṣugbọn nisinsinyii, Timoti ti ti ọ̀dọ̀ yín dé, ó ti fún wa ní ìròyìn rere nípa igbagbọ ati ìfẹ́ yín. Ó ní ẹ̀ ń ranti wa sí rere nígbà gbogbo, ati pé bí ọkàn yin ti ń fà wá, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ti àwa náà ń fà yín. Ará, ìròyìn yìí fún wa ní ìwúrí nípa yín, nítorí igbagbọ yín, a lè gba gbogbo ìṣòro ati inúnibíni tí à ń rí. Nítorí pé bí ẹ bá dúró gbọningbọnin ninu Oluwa nisinsinyii, a jẹ́ pé wíwà láàyè wa kò jẹ́ lásán. Nítorí pé ọpẹ́ mélòó ni a lè dá lọ́wọ́ Ọlọrun nítorí yín, lórí gbogbo ayọ̀ tí à ń yọ̀ nítorí yín níwájú Ọlọrun wa? À ń gbadura kíkankíkan tọ̀sán-tòru pé kí á lè fi ojú kàn yín, kí á lè ṣe àtúnṣe níbi tí igbagbọ yín bá kù kí ó tó. Ǹjẹ́ nisinsinyii, kí Ọlọrun Baba wa fúnrarẹ̀ ati Oluwa wa Jesu kí ó tọ́ ẹsẹ̀ wa sí ọ̀nà dé ọ̀dọ̀ yín. Kí Oluwa mú kí ìfẹ́ yín sí ara yín ati sí gbogbo eniyan kí ó pọ̀ sí i, kí ó sì túbọ̀ jinlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí tiwa ti rí si yín. Kí Oluwa fi agbára fun yín, kí ọkàn yín lè wà ní ipò mímọ́, láìní àléébù, níwájú Ọlọrun Baba wa nígbà tí Oluwa wa Jesu bá farahàn pẹlu gbogbo àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀. Ẹ̀yin ará, ní ìparí ọ̀rọ̀ mi, a fi Jesu Oluwa bẹ̀ yín, a sì rọ̀ yín pé gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gba ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ wa ní ọ̀nà tí ó yẹ, kí ẹ máa rìn bí ó ti wu Ọlọrun. Bí ẹ ti ń ṣe ni kí ẹ túbọ̀ máa ṣe. Nítorí ẹ mọ àwọn ìlànà tí a fun yín, nípa àṣẹ Oluwa Jesu. Nítorí ìfẹ́ Ọlọrun ni pé kí ẹ ya ara yín sí mímọ́: ẹ jìnnà sí àgbèrè. Kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín mọ ọ̀nà láti máa bá aya rẹ̀ gbé pọ̀ pẹlu ìwà mímọ́ ati iyì, kì í ṣe pẹlu ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara bíi ti àwọn abọ̀rìṣà tí kò mọ Ọlọrun. Èyí kò ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fi ojú tẹmbẹlu arakunrin rẹ̀, tabi kí ó ṣẹ arakunrin rẹ̀ nípa ọ̀ràn yìí. Nítorí ẹlẹ́san ni Oluwa ninu àwọn ọ̀ràn wọnyi, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ fun yín tẹ́lẹ̀, tí a wá tún ń kìlọ̀ fun yín nisinsinyii. Nítorí Ọlọrun kò pè wá sí ìwà èérí bíkòṣe ìwà mímọ́. Nítorí náà, ẹni tí ó bá kọ ọ̀rọ̀ yìí, kì í ṣe ọ̀rọ̀ eniyan ni ó kọ̀ bíkòṣe Ọlọrun tí ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ fun yín. Kò nílò pé a tún ń kọ̀wé si yín nípa ọ̀rọ̀ ìfẹ́ láàrin àwọn onigbagbọ, nítorí Ọlọrun ti kọ́ ẹ̀yin fúnra yín láti fẹ́ràn ọmọnikeji yín. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ẹ sì ń ṣe sí gbogbo àwọn onigbagbọ ní gbogbo Masedonia. Ẹ̀yin ará, mò ń rọ̀ yín, ẹ túbọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀ ati jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹ gbìyànjú láti fi ọkàn yín balẹ̀. Ẹ má máa yọjú sí nǹkan oní-ǹkan. Ẹ tẹpá mọ́ṣẹ́, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ fun yín. Ẹ máa rìn bí ó ti yẹ láàrin àwọn alaigbagbọ, kí ó má sí pé ẹ nílò ati gba ohunkohun lọ́wọ́ wọn. Ẹ̀yin ará, àwa kò fẹ́ kí ẹ má ní òye nípa àwọn tí wọ́n ti sùn, kí ẹ má baà banújẹ́ bí àwọn tí kò nírètí. Nítorí bí a bá gbàgbọ́ pé Jesu kú, ó sì jinde, bẹ́ẹ̀ gan-an ni Ọlọrun yóo mú àwọn tí wọ́n ti kú ninu Jesu wà pẹlu rẹ̀. Nítorí à ń sọ ọ̀rọ̀ yìí fun yín gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Oluwa, pé àwa tí a bá wà láàyè, tí a bá kù lẹ́yìn nígbà tí Oluwa bá farahàn, kò ní ṣiwaju àwọn tí wọ́n ti kú. Nítorí nígbà tí ohùn àṣẹ bá dún, Olórí àwọn angẹli yóo fọhùn, fèrè Ọlọrun yóo dún, Oluwa fúnrarẹ̀ yóo sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run. Àwọn òkú ninu Jesu ni yóo kọ́kọ́ jinde. A óo wá gbé àwa tí ó kù lẹ́yìn, tí a wà láàyè, lọ pẹlu wọn ninu awọsanma, láti lọ pàdé Oluwa ní òfuurufú, a óo sì máa wà lọ́dọ̀ Oluwa laelae. Ẹ máa fi ọ̀rọ̀ wọnyi tu ara yín ninu. Ẹ̀yin ará, kò nílò pé a tún ń kọ̀wé si yín mọ́ nípa ti àkókò ati ìgbà tí Oluwa yóo farahàn. Nítorí ẹ̀yin fúnra yín ti mọ̀ dájú pé bí ìgbà tí olè bá dé lóru ni ọjọ́ tí Oluwa yóo dé yóo rí. Nígbà tí àwọn eniyan bá ń wí pé, “Àkókò alaafia ati ìrọ̀ra nìyí,” nígbà náà ni ìparun yóo dé bá wọn lójijì, wọn kò sì ní ríbi sá sí; yóo dàbí ìgbà tí obinrin bá lóyún, tí kò mọ ìgbà tí òun yóo bí. Ẹ̀yin ará, ẹ̀yin kò sí ninu òkùnkùn ní tiyín, tí ọjọ́ náà yóo fi dé ba yín bí ìgbà tí olè bá dé. Nítorí ọmọ ìmọ́lẹ̀ ni gbogbo yín; ọmọ tí a bí ní àkókò tí ojú ti là sí òtítọ́, ẹ kì í ṣe àwọn tí a bí ní àkókò àìmọ̀kan; ẹ kì í ṣe ọmọ òkùnkùn. Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí á máa sùn bí àwọn yòókù, ṣugbọn ẹ jẹ́ kí á máa ṣọ́nà, kí á sì máa ṣọ́ra. Nítorí òru ni àwọn tí ń sùn ń sùn, òru sì ni àwọn tí ó ń mutí ń mutí. Ṣugbọn ní tiwa, ojúmọmọ ni iṣẹ́ tiwa, nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á farabalẹ̀, kí á wọ aṣọ ìgbàyà igbagbọ ati ìfẹ́, kí á dé fìlà ìrètí ìgbàlà. Nítorí Ọlọrun kò pè wá sinu ibinu, ṣugbọn sí inú ìgbàlà nípasẹ̀ Oluwa wa Jesu Kristi, tí ó kú nítorí tiwa, ni ó pè wá sí, pé bí à ń ṣọ́nà ni, tabi a sùn ni, kí á jọ wà láàyè pẹlu rẹ̀. Nítorí náà, ẹ máa tu ara yín ninu, kí ẹ sì máa fún ara yín ní ìwúrí, bí ẹ ti ń ṣe. Ẹ̀yin ará, à ń bẹ̀ yín pé kí ẹ máa bu ọlá fún àwọn tí ń ṣe làálàá láàrin yín, tí wọn ń darí yín nípa ti Oluwa, tí wọn ń gbà yín níyànjú. Ẹ máa fi ìfẹ́ yẹ́ wọn sí gidigidi nítorí iṣẹ́ wọn. Ẹ máa wà ní alaafia láàrin ara yín. Ará, à ń rọ̀ yín pé kí ẹ máa gba àwọn tí ń ṣe ìmẹ́lẹ́ níyànjú; bẹ́ẹ̀ náà ni kí ẹ máa ṣe sí àwọn tí ó ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn; ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́; ẹ máa mú sùúrù pẹlu gbogbo eniyan. Kí ẹ rí i pé ẹnikẹ́ni kò fi burúkú gbẹ̀san burúkú lára ẹnikẹ́ni. Ṣugbọn nígbà gbogbo kí ẹ máa lépa nǹkan rere láàrin ara yín ati láàrin gbogbo eniyan. Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo. Ẹ máa gbadura láì sinmi. Ẹ máa dúpẹ́ ninu ohun gbogbo nítorí èyí ni ìfẹ́ Ọlọrun nípa Kristi Jesu fun yín. Ẹ má máa da omi tútù sí àwọn tí ó ní ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ lọ́kàn. Ẹ má máa fi ojú tẹmbẹlu ẹ̀bùn wolii. Ẹ máa wádìí ohun gbogbo dájú, kí ẹ sì di èyí tí ó bá dára mú ṣinṣin. Ẹ máa takété sí ohunkohun tí ó bá burú. Kí Ọlọrun alaafia kí ó yà yín sí mímọ́ patapata; kí ó pa gbogbo ẹ̀mí yín mọ́ ati ọkàn, ati ara yín. Kí èyíkéyìí má ní àbùkù nígbà tí Oluwa wa Jesu Kristi bá farahàn. Ẹni tí ó pè yín yóo ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé olóòótọ́ ni. Ẹ̀yin ará, ẹ máa gbadura fún wa. Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí gbogbo àwọn onigbagbọ. Mo fi Oluwa bẹ̀ yín, ẹ ka ìwé yìí fún gbogbo ìjọ. Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu Kristi kí ó wà pẹlu yín. Èmi Paulu, ati Silifanu, ati Timoti, ni à ń kọ ìwé yìí sí ìjọ Tẹsalonika, tíí ṣe ìjọ Ọlọrun Baba ati ti Jesu Kristi Oluwa. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba ati Oluwa Jesu Kristi máa wà pẹlu yín. Ẹ̀yin ará, ó yẹ kí á máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nígbà gbogbo nítorí yín. Ó tọ́ bẹ́ẹ̀ nítorí pé igbagbọ yín ń tóbi sí i, ìfẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan yín sí ara yín sì ń pọ̀ sí i. Àwa fúnra wa ń fọ́nnu nípa yín láàrin àwọn ìjọ Ọlọrun. À ń ròyìn ìfaradà ati igbagbọ yín ninu gbogbo inúnibíni ati ìpọ́njú tí ẹ̀ ń faradà. Ìfaradà yín jẹ́ ẹ̀rí ìdájọ́ òdodo Ọlọrun láti kà yín yẹ fún ìjọba rẹ̀ tí ẹ̀ ń tìtorí rẹ̀ jìyà. Nítorí ó tọ́ lójú Ọlọrun láti fi ìpọ́njú san ẹ̀san fún àwọn tí wọn ń pọn yín lójú, ati láti fún ẹ̀yin tí wọn ń pọ́n lójú, ati àwa náà ní ìsinmi, nígbà tí Oluwa wa, Jesu, bá farahàn láti ọ̀run ninu ọwọ́ iná pẹlu àwọn angẹli tí wọ́n jẹ́ alágbára. Nígbà náà ni yóo gbẹ̀san lára àwọn tí kò mọ Ọlọrun ati àwọn tí kò gba ọ̀rọ̀ ìyìn rere Oluwa wa Jesu. Àwọn yìí ni wọn yóo gba ìdálẹ́bi sí ìparun ayérayé, wọn yóo sì kúrò níwájú Oluwa ati ògo agbára rẹ̀; nígbà tí Oluwa bá dé ní ọjọ́ náà láti gba ògo lọ́dọ̀ àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀, nígbà tí gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́ yóo máa yẹ́ ẹ sí, nítorí wọ́n gba ẹ̀rí tí a jẹ́ fún wọn gbọ́. Nítorí èyí ni a fi ń gbadura fun yín nígbà gbogbo, pé kí Ọlọrun wa lè kà yín yẹ fún ìpè tí ó pè yín, kí ó mú èrò gbogbo ṣẹ, kí ó sì fi agbára fun yín láti máa gbé ìgbé-ayé tí ó yẹ onigbagbọ; kí ẹ lè yin orúkọ Oluwa wa Jesu lógo, kí òun náà sì yìn yín, gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun wa ati ti Oluwa Jesu Kristi. Ẹ̀yin ará, à ń bẹ̀ yín nípa ọ̀rọ̀ lórí ìgbà tí Oluwa yóo farahàn ati ìgbà tí yóo kó wa jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín tètè mì, tabi kí èrò yín dàrú lórí ọ̀rọ̀ pé Ọjọ́ Oluwa ti dé. Kì báà jẹ́ pé ninu ọ̀rọ̀ wa tabi ninu Ẹ̀mí ni wọ́n ti rò pé a sọ ọ́, tabi bóyá ninu àlàyékálàyé kan tabi ìwé kan tí wọ́n rò pé ọ̀dọ̀ wa ni ó ti wá. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ lọ́nàkọnà nípa ọ̀rọ̀ yìí. Nítorí kí ọjọ́ Oluwa tó dé, ọ̀tẹ̀ nípa ti ẹ̀sìn níláti kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀, kí Ẹni Ibi nnì, ẹni ègbé nnì sì farahàn. Yóo lòdì sí ohun gbogbo tí ó jẹ́ ti Ọlọrun tabi tí ó jẹ mọ́ ti ẹ̀sìn. Yóo gbé ara rẹ̀ ga ju èyíkéyìí ninu àwọn oriṣa lọ; yóo tilẹ̀ lọ jókòó ninu Tẹmpili Ọlọrun, yóo sì fi ara hàn pé òun ni Ọlọrun. Ẹ ranti pé a ti sọ gbogbo èyí fun yín nígbà tí a wà lọ́dọ̀ yín. Ǹjẹ́ nisinsinyii, ẹ mọ ohun tí ó ń ká a lọ́wọ́ kò, tí kò jẹ́ kí ó farahàn títí àkókò rẹ̀ yóo fi tó. Nítorí nǹkan àṣírí kan tíí máa fa rúkèrúdò ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́, ṣugbọn ẹni tí ó ń ká a lọ́wọ́ kò wà, kò ì kúrò lọ́nà. Nígbà tí ó bá kúrò lọ́nà tán ni Ọkunrin Burúkú nnì yóo wá farahàn. Ṣugbọn Oluwa Jesu yóo fi èémí ẹnu rẹ̀ pa á, yóo sọ ìfarahàn rẹ̀ di asán. Nítorí Ẹni Burúkú yìí yóo farahàn pẹlu agbára Èṣù: yóo máa pidán, yóo ṣe iṣẹ́ àmì, yóo ṣe iṣẹ́ ìtànjẹ tí ó yani lẹ́nu. Yóo fi ọ̀nà àrékérekè burúkú lóríṣìíríṣìí tan àwọn ẹni ègbé jẹ, nítorí wọn kò ní ìfẹ́ òtítọ́, tí wọn ìbá fi rí ìgbàlà. Nítorí èyí, Ọlọrun rán agbára ìtànjẹ sí wọn, kí wọ́n lè gba èké gbọ́, kí gbogbo àwọn tí kò gba òtítọ́ gbọ́ lè gba ìdálẹ́bi, àní, àwọn tí wọ́n ní inú dídùn sí ìwà ibi. Ṣugbọn ó yẹ kí á máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nítorí yín, ẹ̀yin ará, àyànfẹ́ Oluwa, nítorí Ọlọrun ti yàn yín láti ìbẹ̀rẹ̀ wá láti gbà yín là nípa Ẹ̀mí tí ó sọ yín di mímọ́, ati nípa gbígba òtítọ́ gbọ́. Ọlọrun pè yín sí ipò yìí nípa iwaasu wa, kí ẹ lè jogún ògo Oluwa wa Jesu Kristi. Nítorí náà, ẹ̀yin ará, ẹ dúró ṣinṣin, kí ẹ di àwọn ẹ̀kọ́ tí a fi le yín lọ́wọ́ mú, kì báà ṣe àwọn tí a kọ yín nípa ọ̀rọ̀ ẹnu tabi nípa ìwé tí à ń kọ si yín. Bẹ́ẹ̀ ni àwa náà gbà á. Oluwa wa fúnrarẹ̀ ati Ọlọrun Baba wa, tí ó fẹ́ wa, tí ó fún wa ní ìtùnú ayérayé ati ìrètí rere nípa oore-ọ̀fẹ́, yóo tù yín ninu, yóo fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀ ninu oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ati ọ̀rọ̀ rere. Ní ìparí, ẹ̀yin ará, ẹ máa gbadura fún wa, pé kí ọ̀rọ̀ Oluwa lè máa gbilẹ̀, kí ògo rẹ̀ máa tàn sí i, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti rí láàrin yín. Kí ẹ tún máa gbadura pé kí Ọlọrun gbà wá lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú ati àwọn ìkà, nítorí kì í ṣe gbogbo eniyan ni ó gbàgbọ́. Ṣugbọn olódodo ni Oluwa, òun ni yóo fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, tí yóo sì pa yín mọ́ kúrò ninu ibi gbogbo. A ní ìdánilójú ninu Oluwa nípa yín pé àwọn ohun tí a ti sọ, tí ẹ sì ń ṣe, ni ẹ óo máa ṣe. Oluwa yóo tọ́ ọkàn yín láti mọ ìfẹ́ Ọlọrun ati ohun tí Kristi faradà nítorí yín. Ẹ̀yin ará, à ń pàṣẹ fun yín ní orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi pé kí ẹ yẹra fún àwọn onigbagbọ tí wọn bá ń rìn ségesège, tí wọn kò tẹ̀lé ẹ̀kọ́ tí ẹ ti kọ́ lọ́dọ̀ wa. Nítorí ẹ̀yin fúnra yín mọ bí ó ti yẹ kí ẹ ṣe àfarawé wa, nítorí a kò rìn ségesège nígbà tí a wà láàrin yín. Bẹ́ẹ̀ ni a kò jẹ oúnjẹ ẹnikẹ́ni ninu yín lọ́fẹ̀ẹ́. Ṣugbọn ninu làálàá ati ìṣòro ni à ń ṣiṣẹ́ tọ̀sán-tòru, kí á má baà ni ẹnikẹ́ni ninu yín lára. Kì í ṣe pé a kò ní ẹ̀tọ́ láti jẹun lọ́dọ̀ yín; ṣugbọn a kò ṣe bẹ́ẹ̀ kí á lè fi ara wa ṣe àpẹẹrẹ fun yín, kí ẹ lè fara wé wa. Nítorí nígbà tí a wà lọ́dọ̀ yín, a pàṣẹ fun yín pé bí ẹnikẹ́ni bá kọ̀ tí kò ṣiṣẹ́, ẹ má jẹ́ kí ó jẹun. Nítorí a gbọ́ pé àwọn kan ninu yín ń rìn ségesège, wọn kì í ṣiṣẹ́ rárá, ẹsẹ̀ ni wọ́n fi í máa wọ́lẹ̀ kiri. A pàṣẹ fún irú àwọn bẹ́ẹ̀, a tún ń rọ̀ wọ́n ninu Oluwa Jesu Kristi pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ fún oúnjẹ ti ara wọn. Ará, ẹ má ṣe jẹ́ kí rere su yín í ṣe. Bí ẹnikẹ́ni kò bá gbọ́ ọ̀rọ̀ wa ninu ìwé yìí, ẹ wo irú ẹni bẹ́ẹ̀ dáradára. Ẹ má ṣe bá a da nǹkankan pọ̀, kí ó lè yí pada. Ẹ má mú un lọ́tàá, ṣugbọn ẹ máa gbà á níyànjú bí onigbagbọ. Kí Oluwa alaafia fúnrarẹ̀ fun yín ní alaafia nígbà gbogbo lọ́nà gbogbo. Kí Oluwa wà pẹlu gbogbo yín. Èmi Paulu ni mò ń fi ọwọ́ ara mi pàápàá kọ ìwé yìí. Bí èmi ti máa ń kọ̀wé nìyí. Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu Kristi kí ó wà pẹlu gbogbo yín. Èmi Paulu, òjíṣẹ́ Kristi Jesu nípa àṣẹ Ọlọrun Olùgbàlà wa, ati ti Kristi Jesu ìrètí wa, ni mò ń kọ ìwé yìí— Sí Timoti ọmọ mi tòótọ́ ninu igbagbọ. Kí oore-ọ̀fẹ́, àánú ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba, ati Kristi Jesu Oluwa wa, kí ó máa wà pẹlu rẹ. Nígbà tí mò ń lọ sí Masedonia, mo gbà ọ́ níyànjú pé kí o dúró ní Efesu, kí o pàṣẹ fún àwọn kan kí wọn má ṣe kọ́ eniyan ní ẹ̀kọ́ tí ń ṣini lọ́nà, kí wọn má jókòó ti àwọn ìtàn tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ati ìtàn ìrandíran tí kò lópin, tí ó máa ń mú àríyànjiyàn wá, dípò ẹ̀kọ́ nípa Ọlọrun tí a mọ̀ nípa igbagbọ. Ìdí tí mo fi pa àṣẹ yìí ni láti ta ìfẹ́ àtọkànwá jí ninu rẹ, pẹlu ẹ̀rí ọkàn rere ati igbagbọ tí kò lẹ́tàn. Àwọn mìíràn ti kùnà nípa irú èyí; wọ́n ti yipada sí ọ̀rọ̀ asán. Wọn á fẹ́ máa kọ́ni ní òfin, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò mọ ohun tí wọn ń sọ, ohun tí wọ́n sì ń sọ pẹlu ìdánilójú kò yé wọn. A mọ̀ pé òfin jẹ́ ohun tí ó dára bí a bá lò ó bí ó ti tọ́. A mọ èyí pé a kò ṣe òfin fún àwọn eniyan rere, bí kò ṣe fún àwọn oníwàkiwà ati àwọn alágídí, àwọn aláìbọ̀wọ̀ fún Ọlọrun ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, àwọn oníbàjẹ́ ati àwọn aláìbìkítà fún ohun mímọ́, àwọn tí wọn máa ń lu baba ati ìyá wọn, àwọn àgbèrè, àwọn ọkunrin tí ó ń bá ọkunrin lòpọ̀, àwọn gbọ́mọgbọ́mọ, àwọn onírọ́, àwọn tí ó ń búra èké, ati àwọn tí ń ṣe àwọn nǹkan mìíràn tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ó dára, gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere tí a fi lé mi lọ́wọ́, ìyìn rere Ọlọrun Ológo, tí ìyìn yẹ fún. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Kristi Jesu Oluwa wa, ẹni tí ń fún mi ní agbára. Mo dúpẹ́ nítorí ó kà mí yẹ láti fún mi ní iṣẹ́ rẹ̀, èmi tí ó jẹ́ pé tẹ́lẹ̀ rí mo kẹ́gàn rẹ̀, mo ṣe inúnibíni sí i, mo tún fi àbùkù kàn án. Ṣugbọn ó ṣàánú mi nítorí n kò mọ̀ọ́nmọ̀ ṣe é; ninu aigbagbọ ni mo ṣe é. Ṣugbọn oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa pàpọ̀jù lórí mi, ati igbagbọ ati ìfẹ́ tí a ní ninu Kristi Jesu. Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí: ó dájú, ó sì yẹ ní gbígbà tọkàntọkàn, pé Kristi Jesu wá sinu ayé láti gba ẹlẹ́ṣẹ̀ là. Èmi yìí sì ni olórí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. Ìdí tí ó fi ṣàánú mi nìyí, pé èmi ni Kristi Jesu kọ́kọ́ yọ́nú sí ju ẹnikẹ́ni lọ. Mo wá di àpẹẹrẹ gbogbo àwọn tí wọn yóo gbà á gbọ́ tí wọn yóo sì ní ìyè ainipẹkun. Kí ọlá ati ògo jẹ́ ti Ọba ayérayé, Ọba àìkú, Ọba àìrí, Ọlọrun kan ṣoṣo, lae ati laelae. Amin. Timoti ọmọ mi, ọ̀rọ̀ àṣẹ yìí ni mo fi lé ọ lọ́wọ́, gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ tí àwọn wolii sọ nípa rẹ̀ tí mo fi yàn ọ́, pé kí o ja ìjà rere pẹlu agbára àṣẹ yìí. Kí o fi igbagbọ ati ẹ̀rí-ọkàn rere jà. Àwọn nǹkan wọnyi ni àwọn mìíràn kọ̀, tí ọkọ̀ ìgbé-ayé igbagbọ wọn fi rì. Irú àwọn bẹ́ẹ̀ ní Himeneu ati Alẹkisanderu, àwọn tí mo ti fà lé Satani lọ́wọ́ kí ó lè bá wọn wí kí wọn má ṣe sọ̀rọ̀ àbùkù mọ́. Nítorí náà, lákọ̀ọ́kọ́, mo gbà ọ́ níyànjú pé kí o máa tọrọ ninu adura, kí o máa bẹ̀bẹ̀, kí o sì máa dúpẹ́ fún gbogbo eniyan, fún àwọn ọba, ati fún gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ipò gíga, pé kí á máa ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, kí á máa gbé ìgbé-ayé bí olùfọkànsìn ati bí ọmọlúwàbí. Irú adura báyìí dára, ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọrun Olùgbàlà wa, ẹni tí ó fẹ́ kí gbogbo eniyan rí ìgbàlà, tí ó sì fẹ́ kí wọn ní ìmọ̀ òtítọ́. Nítorí Ọlọrun kan ni ó wà, alárinà kan ni ó sì wà láàrin Ọlọrun ati eniyan; olúwarẹ̀ ni Kristi Jesu, tí òun náà jẹ́ eniyan, tí ó fi ara rẹ̀ ṣe ìràpadà fún gbogbo eniyan. Èyí ni ẹ̀rí pé, Ọlọrun ṣe ètò pé kí gbogbo eniyan lè ní ìgbàlà nígbà tí àkókò rẹ̀ tó. Òtítọ́ ni mò ń sọ, n kò purọ́, pé ohun tí a yàn mí láti jẹ́ akéde ati aposteli sí ni pé kí n jẹ́ olùkọ́ni fún àwọn tí kì í ṣe Juu nípa nǹkan tí ó jẹ mọ́ igbagbọ ati òtítọ́ Ọlọrun. Nítorí náà mo fẹ́ kí gbogbo eniyan máa gbadura ninu gbogbo ìsìn, kí wọn máa gbé ọwọ́ adura sókè pẹlu ọkàn kan, láìsí èrò ibinu tabi ọkàn àríyànjiyàn. Bákan náà, kí àwọn obinrin wọ aṣọ bí ó ti yẹ, aṣọ tí kò ní ti eniyan lójú, kí wọ́n ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́ níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Kí wọn má ṣe di irun wọn ní aláràbarà fún àṣehàn. Kí wọn má ṣe kó ohun ọ̀ṣọ́ bíi wúrà ati ìlẹ̀kẹ̀ tabi aṣọ olówó ńlá sára. Ṣugbọn kí ọ̀ṣọ́ wọn jẹ́ ọpọlọpọ iṣẹ́ rere, bí ó ti yẹ fún àwọn obinrin olùfọkànsìn. Obinrin níláti máa fi ìfarabalẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ pẹlu ìtẹríba. N kò gbà fún obinrin láti jẹ́ olùkọ́ni tabi láti ní àṣẹ lórí ọkunrin. Kí obinrin máa panumọ́ ni. Nítorí Adamu ni a kọ́kọ́ dá, kí á tó dá Efa. Kì í sì í ṣe Adamu ni a tàn jẹ, obinrin ni a tàn jẹ tí ó fi di ẹlẹ́ṣẹ̀. Ṣugbọn a óo gba obinrin là nípa ọmọ-bíbí, bí àwọn obinrin bá dúró láì yẹsẹ̀ ninu igbagbọ ati ìfẹ́ ati ìwà mímọ́ pẹlu ìwà ìkóra-ẹni-níjàánu. Òdodo ọ̀rọ̀ nìyí: bí ẹnikẹ́ni bá dàníyàn láti jẹ́ olùdarí, iṣẹ́ rere ni ó fẹ́ ṣe. Nítorí náà, olùdarí níláti jẹ́ ẹni tí kò lẹ́gàn; kò gbọdọ̀ ní ju iyawo kan lọ, ó gbọdọ̀ jẹ́ eniyan jẹ́jẹ́, ọlọ́gbọ́n eniyan, ọmọlúwàbí, ẹni tí ó fẹ́ràn láti máa ṣe eniyan lálejò, tí ó sì fẹ́ràn iṣẹ́ olùkọ́ni. Kò gbọdọ̀ jẹ́ ọ̀mùtí, tabi ẹni tí máa ń lu eniyan. Ṣugbọn kí ó jẹ́ onífaradà. Kò gbọdọ̀ jẹ́ alásọ̀, tabi ẹni tí ó ní ọ̀kánjúwà owó. Ó gbọdọ̀ káwọ́ ilé rẹ̀ dáradára, kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa gbọ́ràn sí i lẹ́nu tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Nítorí ẹni tí kò káwọ́ ilé ara rẹ̀, báwo ni ó ṣe lè mójútó ìjọ Ọlọrun? Kí ó má jẹ́ ẹni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ di onigbagbọ, kí ó má baà gbéraga, kí ó wá bọ́ sọ́wọ́ Satani. Ṣugbọn kí ó jẹ́ ẹni tí ó ní ẹ̀rí rere lọ́dọ̀ àwọn tí kì í ṣe onigbagbọ, kí ó má baà bọ̀ sinu ẹ̀gàn, kí tàkúté Satani má baà mú un. Bákan náà ni kí àwọn diakoni jẹ́ oníwà pẹ̀lẹ́. Kí wọn má ṣe jẹ́ ẹlẹ́nu meji. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí ó ń mutí para. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ oníwọ̀ra eniyan. Wọ́n níláti di ohun ìjìnlẹ̀ igbagbọ mú pẹlu ẹ̀rí-ọkàn tí ó mọ́. A sì níláti kọ́kọ́ dán wọn wò ná; bí wọ́n bá jẹ́ aláìlẹ́gàn, kí á wá fi wọ́n sí ipò diakoni. Bákan náà ni àwọn obinrin níláti jẹ́ oníwà pẹ̀lẹ́; kí wọn má jẹ́ abanijẹ́. Kí wọn jẹ́ eniyan jẹ́jẹ́, kí wọn jẹ́ ẹni tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ninu ohun gbogbo. Diakoni kò gbọdọ̀ ní ju aya kan lọ; ó sì gbọdọ̀ káwọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ dáradára ati gbogbo ìdílé rẹ̀. Nítorí àwọn tí wọn bá ṣe iṣẹ́ diakoni dáradára ti ṣí ọ̀nà ipò gíga fún ara wọn. Wọ́n lè sọ̀rọ̀ pẹlu ọpọlọpọ ìgboyà nípa igbagbọ tí ó wà ninu Kristi Jesu. Mo ní ìrètí láti wá sọ́dọ̀ rẹ láìpẹ́, ṣugbọn mò ń kọ ìwé yìí, nítorí bí mo bá pẹ́ kí n tó wá, kí o lè mọ̀ bí ó ti yẹ láti darí ètò ilé Ọlọrun, èyí tíí ṣe ìjọ Ọlọrun alààyè, òpó ati ààbò òtítọ́. Kò sí ẹni tí kò mọ̀ pé àṣírí ẹ̀sìn wa jinlẹ̀ pupọ: Ẹni tí ó farahàn ninu ẹran-ara, tí a dá láre ninu ẹ̀mí, tí àwọn angẹli fi ojú rí, tí à ń waasu rẹ̀ láàrin àwọn alaigbagbọ, tí a gbàgbọ́ ninu ayé, tí a gbé lọ sinu ògo. Ẹ̀mí sọ pàtó pé nígbà tí ó bá yá, àwọn ẹlòmíràn yóo yapa kúrò ninu ẹ̀sìn igbagbọ, wọn yóo tẹ̀lé àwọn ẹ̀mí ẹ̀tàn ati ẹ̀kọ́ tí ó ti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí èṣù wá. Ẹnu àwọn àgàbàgebè eniyan ni ẹ̀kọ́ burúkú wọnyi yóo ti wá, àwọn tí wọn ń sọ̀rọ̀ èké; àwọn tí Satani ń darí ẹ̀rí-ọkàn wọn. Irú wọn ni wọ́n ń sọ pé kí eniyan má ṣe gbeyawo. Wọ́n ní kí eniyan má ṣe jẹ àwọn oríṣìí oúnjẹ kan, bẹ́ẹ̀ sì ni Ọlọrun ni ó dá a pé kí àwọn onigbagbọ ati àwọn tí wọ́n mọ òtítọ́ máa jẹ ẹ́ pẹlu ọpẹ́. Nítorí ohun gbogbo tí Ọlọrun dá ni ó dára. Kò sí ohun tí a gbọdọ̀ kọ̀ bí a bá gbà á pẹlu ọpẹ́, nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọrun ati adura ti sọ ọ́ di mímọ́. Bí o bá ń fi irú ọ̀rọ̀ báyìí siwaju àwọn arakunrin, ìwọ yóo jẹ́ òjíṣẹ́ rere ti Kristi Jesu, tí a tọ́ dàgbà ninu ọ̀rọ̀ igbagbọ ati ẹ̀kọ́ rere tí ò ń tẹ̀lé. Má jẹ́ kí á bá ọ ní ìdí ìtàn àgbọ́sọ tí kò wúlò ati àwọn ìtànkítàn tí àwọn ìyá arúgbó fẹ́ràn. Ṣe ara rẹ yẹ fún ìgbé-ayé eniyan Ọlọrun. Eniyan a máa rí anfaani níwọ̀nba tí ó bá ń ṣe eré ìdárayá ti ara, ṣugbọn anfaani ti ẹ̀mí kò lópin; nítorí ó ní anfaani ní ayé yìí, ó tún fún eniyan ní anfaani ti ayé tí ń bọ̀. Òdodo ọ̀rọ̀ nìyí, ó sì yẹ kí eniyan gbà á tọkàntọkàn. Ìdí tí a fi ń ṣe làálàá nìyí, tí a sì ń jìjàkadì, nítorí a gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun alààyè, ẹni tí ó jẹ́ Olùgbàlà gbogbo eniyan, pàápàá jùlọ ti àwọn onigbagbọ. Àwọn nǹkan wọnyi ni kí o máa pa láṣẹ, kí o sì máa kọ́ àwọn eniyan. Má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kẹ́gàn rẹ, nítorí pé o jẹ́ ọ̀dọ́. Ṣugbọn jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn onigbagbọ ninu ọ̀rọ̀ rẹ, ati ninu ìṣe rẹ, ninu ìfẹ́, ninu igbagbọ ati ninu ìwà pípé. Kí n tó dé, tẹra mọ́ kíka ọ̀rọ̀ Ọlọrun, ati gbígba àwọn eniyan níyànjú, ati iṣẹ́ olùkọ́ni. Má ṣe àìnáání ẹ̀bùn tí Ẹ̀mí Mímọ́ fún ọ nípa àsọtẹ́lẹ̀ nígbà tí àwọn àgbà ìjọ gbé ọwọ́ lé ọ lórí. Máa lépa àwọn nǹkan wọnyi. Àwọn ni kí o jẹ́ kí ó gba gbogbo àkókò rẹ, kí ìtẹ̀síwájú rẹ lè hàn sí gbogbo eniyan. Máa ṣọ́ ara rẹ ati ẹ̀kọ́ rẹ. Dúró ṣinṣin ninu wọn. Tí o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóo gba ara rẹ là ati àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ. Má máa fi ohùn líle bá àwọn àgbàlagbà wí, ṣugbọn máa gbà wọ́n níyànjú bíi baba rẹ. Máa ṣe sí àwọn ọdọmọkunrin bí ẹ̀gbọ́n ati àbúrò rẹ. Mú àwọn àgbà obinrin bí ìyá; mú àwọn ọ̀dọ́ obinrin bí ẹ̀gbọ́n tabi àbúrò rẹ pẹlu ìwà mímọ́ ní ọ̀nà gbogbo. Bu ọlá fún àwọn opó tí wọ́n jẹ́ alailẹnikan. Ṣugbọn bí opó kan bá ní àwọn ọmọ tabi àwọn ọmọ-ọmọ, wọ́n gbọdọ̀ kọ́ láti ṣe ìtọ́jú ìdílé wọn, kí wọ́n san pada ninu ohun tí àwọn òbí wọn ti ṣe fún wọn. Èyí ni ohun tí ó dára lójú Ọlọrun. Ṣugbọn ẹni tí ó bá jẹ́ opó nítòótọ́, tí kò ní ọmọ tabi ọmọ-ọmọ, Ọlọrun nìkan ni ó ń wò, tí ó ń bẹ̀, tí ó ń gbadura sí tọ̀sán-tòru. Ṣugbọn opó tí ó bá ń gbádùn ara rẹ̀ káàkiri ti kú sáyé. Àwọn ohun tí o óo máa pa láṣẹ nìyí, kí wọ́n lè jẹ́ aláìlẹ́gàn. Bí ẹnìkan kò bá pèsè fún àwọn ẹbí rẹ̀, pataki jùlọ fún àwọn ìdílé rẹ̀, olúwarẹ̀ ti lòdì sí ẹ̀sìn igbagbọ wa, ó sì burú ju alaigbagbọ lọ. Má kọ orúkọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀ bí opó àfi ẹni tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò bá dín ní ọgọta ọdún, tí ó sì jẹ́ aya ọkọ kan, tí a jẹ́rìí sí iṣẹ́ rere rẹ̀, tí ó tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ dáradára, tí ó máa ń ṣe eniyan lálejò, tí kò sí iṣẹ́ tí ó kéré jù tí kò lè ṣe fún àwọn onigbagbọ, tí ó ti ran àwọn tí ó wà ninu ìyọnu lọ́wọ́. Ní kúkúrú, kí ó jẹ́ ẹni tí ń ṣe iṣẹ́ rere nígbà gbogbo. Ṣọ́ra nípa kíkọ orúkọ àwọn opó tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ sílẹ̀, nítorí nígbà tí ara wọn bá gbóná, wọn yóo kọ ètò ti Kristi sílẹ̀, wọn yóo fẹ́ tún lọ́kọ. Wọn yóo wá gba ẹ̀bi nítorí wọ́n ti kọ ẹ̀jẹ́ wọn àkọ́kọ́ sílẹ̀. Ati pé nígbà tí wọn bá ń tọ ojúlé kiri, wọ́n ń kọ́ láti ṣe ìmẹ́lẹ́. Kì í sì í ṣe ìmẹ́lẹ́ nìkan, wọn a máa di olófòófó ati alátojúbọ̀ ọ̀ràn-ọlọ́ràn, wọn a sì máa sọ ohun tí kò yẹ. Nítorí náà mo fẹ́ kí àwọn opó tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ tún lọ́kọ, kí wọ́n bímọ, kí wọ́n ní ilé tiwọn. Bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀ wọn kò ní fi ààyè sílẹ̀ fún ọ̀tá láti sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́. Nítorí àwọn mìíràn ti yipada, wọ́n ti ń tẹ̀lé Satani. Bí onigbagbọ obinrin kan bá ní àwọn opó ninu ẹbí rẹ̀, òun ni ó níláti ṣe ìtọ́jú wọn. Kò níláti di ẹrù wọn lé ìjọ Ọlọrun lórí, kí ìjọ lè mójútó àwọn tí wọ́n jẹ́ opó gidi. Ó yẹ kí àwọn àgbà tí wọ́n bá ṣe iṣẹ́ aṣiwaju dáradára gba ìdálọ́lá ọ̀nà meji, pataki jùlọ àwọn tí wọn ń ṣe iṣẹ́ oníwàásù ati olùkọ́ni. Nítorí Ìwé Mímọ́ sọ pé, “Má ṣe dí mààlúù tí ó ń tẹ ọkà lẹ́nu.” Ati pé, “Owó oṣù òṣìṣẹ́ tọ́ sí i.” Bí ẹnìkan bá fi ẹ̀sùn kan àgbàlagbà, má ṣe kà á sí àfi tí ẹlẹ́rìí meji tabi mẹta bá wà. Bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ wí ní gbangba, kí ẹ̀rù lè ba àwọn yòókù. Mo sọ fún ọ, níwájú Ọlọrun ati Kristi Jesu, ati àwọn angẹli tí Kristi ti yàn, pé kí o pa ọ̀rọ̀ yìí mọ́; má ṣe ojuṣaaju. Má fi ìwàǹwára gbé ọwọ́ lé ẹnikẹ́ni lórí láti fi jẹ oyè ninu ìjọ, má sì di alábàápín ninu ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíràn. Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ mọ́. Má máa mu omi nìkan, ṣugbọn máa lo waini díẹ̀, nítorí inú tí ń yọ ọ́ lẹ́nu ati nítorí àìsàn tí ó máa ń ṣe ọ́ nígbà gbogbo. Àwọn kan wà tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn hàn sí gbogbo eniyan, àwọn adájọ́ ti mọ̀ wọ́n kí wọ́n tó mú wọn dé kọ́ọ̀tù. Ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíràn a máa pẹ́ kí ó tó hàn sóde. Bákan náà ni, iṣẹ́ rere a máa hàn sí gbogbo eniyan. Bí wọn kò bá tilẹ̀ tíì hàn, wọn kò ṣe é bò mọ́lẹ̀ títí. Àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ àjàgà ẹrú níláti rí i pé wọ́n ń bu ọlá fún àwọn ọ̀gá wọn ní ọ̀nà gbogbo, kí àwọn eniyan má baà sọ̀rọ̀ ìṣáátá sí orúkọ Ọlọrun ati ẹ̀kọ́ onigbagbọ. Àwọn ẹrú tí wọ́n ní ọ̀gá onigbagbọ kò gbọdọ̀ sọ ara wọn di ẹgbẹ́ ọ̀gá wọn, wọn ìbáà jẹ́ ará ninu Kristi. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n níláti sìn wọ́n tara-tara, nítorí àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́ fún jẹ́ arakunrin ninu igbagbọ ati ìfẹ́. Àwọn nǹkan wọnyi ni kí o máa fi kọ́ àwọn eniyan, kí o sì máa fi gbà wọ́n níyànjú. Bí ẹnìkan bá ń kọ́ àwọn eniyan ní ẹ̀kọ́ mìíràn, tí kò mọ ẹ̀kọ́ tí ó yè, ẹ̀kọ́ ti Oluwa wa Jesu Kristi, ati ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn tí ó pé, ìgbéraga ti sọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ di aṣiwèrè, kò sì mọ nǹkankan. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ óo fẹ́ràn láti máa ṣe òfintótó ọ̀ràn, ati iyàn jíjà, àwọn ohun tí ó ń mú owú-jíjẹ, ìjà, ìsọkúsọ, ìfura burúkú, ati àríyànjiyàn wá. Nǹkan wọnyi wọ́pọ̀ láàrin àwọn tí orí wọn ti kú, tí wọ́n ti yapa kúrò ní ọ̀nà òtítọ́. Wọ́n rò pé nítorí èrè ni eniyan fi ń ṣe ẹ̀sìn. Òtítọ́ ni pé èrè ńlá wà ninu jíjẹ́ olùfọkànsìn, tí eniyan bá ní ìtẹ́lọ́rùn. Nítorí a kò mú ohunkohun wá sinu ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò lè mú ohunkohun kúrò ninu rẹ̀. Bí a bá ti ní oúnjẹ ati aṣọ, kí á ní ìtẹ́lọ́rùn pẹlu wọn. Àwọn tí wọn ń fẹ́ di ọlọ́rọ̀ a máa ṣubú sinu ìdánwò, tàkúté a sì mú wọn. Wọn a máa lépa ọpọlọpọ nǹkan tí kò mú ọgbọ́n wá ati àwọn nǹkan tí ó lè pa eniyan lára, irú nǹkan tí ó ti mú kí àwọn mìíràn jìn sinu ọ̀fìn ikú ati ìparun. Ìfẹ́ owó ni ìpìlẹ̀ gbogbo nǹkan burúkú. Èyí ni àwọn mìíràn ń lépa tí wọ́n fi ṣìnà kúrò ninu igbagbọ, tí wọ́n sì fi ọwọ́ ara wọn fa ọpọlọpọ ìbànújẹ́ fún ara wọn. Ṣugbọn ìwọ eniyan Ọlọrun, sá fún nǹkan wọnyi. Máa lépa òdodo, ati ìfọkànsìn Ọlọrun, igbagbọ, ìfẹ́, ìfaradà, ati ìwà pẹ̀lẹ́. Máa ja ìjà rere ti igbagbọ. Di ìyè ainipẹkun mú. Ohun tí Ọlọrun pè ọ́ fún nìyí, òun sì ni ẹ̀rí rere tí o fi ẹnu ara rẹ jẹ́ níwájú ọpọlọpọ ẹlẹ́rìí. Mo pá a láṣẹ fún ọ níwájú Ọlọrun tí ó fi ẹ̀mí sinu gbogbo ohun alààyè, ati níwájú Kristi Jesu tí òun náà jẹ́rìí rere níwájú Pọntiu Pilatu, pé kí o mú gbogbo àṣẹ tí o ti gbà ṣẹ láìsí àléébù ati láìsí ẹ̀gàn títí Oluwa wa Jesu Kristi yóo fi farahàn. Ọlọrun yóo mú ìfihàn yìí wá ní àkókò tí ó bá wù ú, òun ni aláṣẹ kanṣoṣo, Ọba àwọn ọba ati Oluwa àwọn oluwa; òun nìkan tí kì í kú, tí ó ń gbé inú ìmọ́lẹ̀ tí eniyan kò lè súnmọ́, tí ẹnikẹ́ni kò rí rí, tí eniyan kò tilẹ̀ lè rí. Tirẹ̀ ni ọlá ati agbára tí kò lópin. Amin. Mo pa á láṣẹ fún àwọn ọlọ́rọ̀ ayé yìí, pé kí wọ́n má ṣe ní ọkàn gíga. Bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n má ṣe gbára lé ọrọ̀ tí kò lágbẹkẹ̀lé, ṣugbọn kí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun tí ó ń fún wa ní gbogbo ọrọ̀ fún ìgbádùn wa. Kí wọn máa ṣe rere, kí wọn jẹ́ ọlọ́rọ̀ ninu iṣẹ́ rere, kí wọn fẹ́ràn láti máa ṣe ọrẹ ati láti máa mú ninu ohun ìní wọn fún àwọn ẹlòmíràn, kí wọ́n lè ní ìṣúra fún ara wọn tí yóo jẹ́ ìpìlẹ̀ rere fún ẹ̀yìn ọ̀la, kí ọwọ́ wọn lè tẹ ìyè tòótọ́. Timoti mi ọ̀wọ́n, pa ìṣúra tí a fi fún ọ mọ́. Di etí rẹ sí àwọn ọ̀rọ̀ játijàti tí kò ṣeni ní anfaani ati àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn kan ń ṣì pè ní ọ̀rọ̀ ọgbọ́n. Àṣìpè ni, nítorí pé wọ́n kún fún àwọn ẹ̀kọ́ tí ó lòdì sí ara wọn. Àwọn mìíràn tí wọ́n tẹ̀lé irú ọ̀nà yìí ti ṣìnà kúrò ninu igbagbọ. Kí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun wà pẹlu yín. Èmi Paulu, aposteli Kristi Jesu, nípa ìfẹ́ Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ìlérí ìyè tí ó wà ninu Kristi Jesu, èmi ni mò ń kọ ìwé yìí— Sí Timoti, àyànfẹ́ ọmọ mi. Kí oore-ọ̀fẹ́, àánú ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba, ati Kristi Jesu, Oluwa wa, wà pẹlu rẹ. Nígbà tí mo bá ń ranti rẹ ninu adura mi tọ̀sán-tòru, èmi a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun tí mò ń sìn pẹlu ẹ̀rí-ọkàn mímọ́, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba-ńlá mi ti ṣe. Nígbà tí mo bá ranti ẹkún tí o sun, a dàbí kí n tún rí ọ, kí ayọ̀ mi lè di kíkún. Mo ranti igbagbọ rẹ tí kò lẹ́tàn, tí ó kọ́kọ́ wà ninu Loisi ìyá-ìyá rẹ, ati ninu Yunisi ìyá rẹ, tí ó sì dá mi lójú pé ó wà ninu ìwọ náà. Ìdí nìyí tí mo fi ń rán ọ létí pé kí o máa rú ẹ̀bùn-ọ̀fẹ́ Ọlọrun sókè, tí a fi fún ọ nípa ọwọ́ mi tí mo gbé lé ọ lórí. Nítorí kì í ṣe ẹ̀mí ojo ni Ọlọrun fún wa bíkòṣe ẹ̀mí agbára ati ti ìfẹ́ ati ti ìkóra-ẹni-níjàánu. Nítorí náà má ṣe tijú láti jẹ́rìí fún Oluwa wa tabi fún èmi tí mo wà lẹ́wọ̀n nítorí rẹ̀. Ṣugbọn gba ìjìyà tìrẹ ninu iṣẹ́ ìyìn rere pẹlu agbára Ọlọrun, tí ó gbà wá là, tí ó pè wá láti ya ìgbé-ayé wa sọ́tọ̀. Kì í ṣe pé ìwà wa ni ó dára tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi pè wá. Ṣugbọn ó pè wá gẹ́gẹ́ bí ètò tí òun fúnrarẹ̀ ti ṣe, ati nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí ó fi fún wa nípasẹ̀ Kristi Jesu láti ayérayé. Ètò yìí ni ó wá hàn kedere nisinsinyii nípa ìfarahàn olùgbàlà wa Kristi Jesu, tí ó gba agbára lọ́wọ́ ikú, tí ó mú ìyè ati àìkú wá sinu ìmọ́lẹ̀ nípa ìyìn rere. Ọlọrun yàn mí láti jẹ́ akéde ati aposteli ati olùkọ́ni. Ìdí nìyí tí mo fi ń jìyà báyìí. Ṣugbọn ojú kò tì mí. Nítorí mo mọ ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé. Ó sì dá mi lójú pé ó lè pa ìṣúra tí mo fi pamọ́ sí i lọ́wọ́ mọ́ títí di ọjọ́ ńlá náà. Di àpẹẹrẹ ẹ̀kọ́ tí ó yẹ, tí o ti gbà láti ọ̀dọ̀ mi mú, pẹlu igbagbọ ati ìfẹ́ tí ó wà ninu Kristi Jesu. Pa ìṣúra rere náà mọ́ pẹlu agbára Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó ń gbé inú rẹ. O kò ní ṣàìmọ̀ pé gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní agbègbè Esia ti sá kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ó fi mọ́ Fugẹlọsi ati Hemogenesi. Kí Oluwa ṣàánú ìdílé Onesiforosi. Kò ní iye ìgbà tí ó ti tù mí ninu, ninu ìṣòro mi. Kò tijú pé ẹlẹ́wọ̀n ni mí. Nígbà tí ó dé Romu, ó fi ìtara wá mi kàn, ó sì rí mi. Kí Oluwa jẹ́ kí ó lè rí àánú rẹ̀ gbà ní ọjọ́ ńlá náà. Iṣẹ́ iranṣẹ tí ó ṣe ní Efesu kò ṣe àjèjì sí ìwọ alára. Nítorí náà, ìwọ ọmọ mi, jẹ́ kí oore-ọ̀fẹ́ tí ó wà ninu ìdàpọ̀ pẹlu Kristi Jesu sọ ọ́ di alágbára. Àwọn ohun tí o gbọ́ láti ẹnu mi níwájú ọpọlọpọ ẹlẹ́rìí, ni kí o fi lé àwọn olóòótọ́ eniyan lọ́wọ́, àwọn tí ó tó láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Farada ìpín tìrẹ ninu ìṣòro gẹ́gẹ́ bí ọmọ-ogun Kristi Jesu. Kò sí ọmọ-ogun tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ tí ó gbọdọ̀ tún tojú bọ àwọn nǹkan ayé yòókù. Àníyàn rẹ̀ kanṣoṣo ni láti tẹ́ ọ̀gágun rẹ̀ lọ́rùn. Kò sí ẹni tí ó bá ń súré ìje tí ó lè gba èrè àfi bí ó bá pa òfin iré ìje mọ́. Àgbẹ̀ tí ń ṣiṣẹ́ lóko ni ó kọ́ ní ẹ̀tọ́ sí ìkórè oko. Gba ohun tí mò ń sọ rò. Oluwa yóo jẹ́ kí ìtumọ̀ rẹ̀ yé ọ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Ranti Jesu Kristi tí a jí dìde kúrò ninu òkú, tí a bí ninu ìdílé Dafidi. Ìyìn rere tí mò ń waasu nìyí. Ninu iṣẹ́ yìí ni mo ti ń jìyà títí mo fi di ẹlẹ́wọ̀n bí ọ̀daràn. Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó lè fi ẹ̀wọ̀n de ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Nítorí náà, mo farada ohun gbogbo nítorí àwọn àyànfẹ́, kí àwọn náà lè rí ìgbàlà tí ó wà ninu Kristi Jesu pẹlu ògo tí ó wà títí lae. Òdodo ọ̀rọ̀ nìyí, pé, “Bí a bá bá a kú, a óo wà láàyè pẹlu rẹ̀. Bí a bá faradà á, a óo bá a jọba. Bí a bá sẹ́ ẹ, òun náà yóo sẹ́ wa. Bí àwa kò bá tilẹ̀ ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, òun ṣe é gbẹ́kẹ̀lé nígbà gbogbo, nítorí òun kò lè tan ara rẹ̀ jẹ.” Máa rán àwọn eniyan létí nípa nǹkan wọnyi. Kìlọ̀ fún wọn níwájú Ọlọrun pé kí wọn má máa jiyàn lórí oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ tí kò wúlò, tíí sìí máa da àwọn tí ó bá gbọ́ lọ́kàn rú. Sa gbogbo ipá rẹ láti ṣe ara rẹ ní ẹni tí ó yege níwájú Ọlọrun, gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ tí kò ṣe ohun ìtìjú pamọ́, tí ó ń sọ ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí ó ti yẹ. Yẹra fún àwọn ọ̀rọ̀ asán ati ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ, nítorí àwọn tí wọ́n fẹ́ràn irú ọ̀rọ̀ wọnyi túbọ̀ ń jìnnà sí ẹ̀sìn Ọlọrun ni. Ọ̀rọ̀ wọn dàbí egbò-rírùn tí ó ń kẹ̀ siwaju. Irú wọn ni Himeneu ati Filetu, àwọn tí wọ́n ti ṣìnà kúrò ninu òtítọ́, tí wọn ń sọ pé ajinde tiwa ti ṣẹlẹ̀, tí wọn ń mú kí igbagbọ ẹlòmíràn yẹ̀. Ṣugbọn Ọlọrun ti fi ìpìlẹ̀ yìí lélẹ̀, tí ó dúró gbọningbọnin. Àkọlé tí a kọ sára èdìdì tí ó wà lára rẹ̀ nìyí: “Ọlọrun mọ àwọn ẹni tirẹ̀,” ati pé, “Gbogbo àwọn tí ó bá ń pe orúkọ Oluwa níláti kúrò ninu ibi.” Kì í ṣe àwọn ohun èèlò wúrà ati ti fadaka nìkan ni ó ń wà ninu ilé ńlá. Àwọn nǹkan tí wọ́n fi igi ati amọ̀ ṣe wà níbẹ̀ pẹlu. À ń lo àwọn kan fún nǹkan pataki; à ń lo àwọn mìíràn fún ohun tí kò ṣe pataki tóbẹ́ẹ̀. Bí ẹnikẹ́ni bá wẹ ara rẹ̀ mọ́ kúrò ninu àwọn nǹkan wọnyi, olúwarẹ̀ yóo di ohun èèlò tí ó níye lórí, tí a yà sọ́tọ̀, tí ó wúlò fún baálé ilé. Yóo di ẹni tí ó ṣetán láti ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ rere. Yẹra fún àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọ̀dọ́. Máa lépa òdodo ati ìṣòtítọ́, ìfẹ́, ati alaafia, pẹlu àwọn tí ó ń képe Oluwa pẹlu ọkàn mímọ́. Má bá wọn lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ ati ọ̀rọ̀ òpè. Ranti pé ìjà ni wọ́n ń dá sílẹ̀. Iranṣẹ Oluwa kò sì gbọdọ̀ jà. Ṣugbọn ó níláti máa ṣe jẹ́jẹ́ sí gbogbo eniyan, kí ó jẹ́ olùkọ́ni rere, tí ó ní ìfaradà. Kí ó fi ìfarabalẹ̀ bá àwọn tí ó bá lòdì sí i wí, bóyá Ọlọrun lè fún wọn ní ọkàn ìrònúpìwàdà, kí wọ́n lè ní ìmọ̀ òtítọ́, kí wọ́n lè bọ́ kúrò ninu tàkúté Satani, tí ó ti fi mú wọn láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Kí o mọ èyí pé àkókò ìṣòro ni ọjọ́ ìkẹyìn yóo jẹ́. Nítorí àwọn eniyan yóo wà tí ó jẹ́ pé ara wọn ati owó nìkan ni wọn óo fẹ́ràn. Wọn óo jẹ́ oníhàlẹ̀, onigbeeraga, ati onísọkúsọ. Wọn yóo máa ṣe àfojúdi sí àwọn òbí wọn. Wọn óo jẹ́ aláìmoore; aláìbọ̀wọ̀ fún Ọlọrun, onínú burúkú; akọ̀mágbẹ̀bẹ̀, abanijẹ́; àwọn tí kò lè kó ara wọn níjàánu, òǹrorò; àwọn tí kò fẹ́ ohun rere; ọ̀dàlẹ̀, jàǹdùkú, àwọn tí ó jọ ara wọn lójú pupọ, àwọn tí wọ́n fẹ́ràn fàájì, dípò kí wọ́n fẹ́ràn Ọlọrun. Ní òde, ara wọn dàbí olùfọkànsìn, ṣugbọn wọn kò mọ agbára ẹ̀sìn tòótọ́. Ìwọ jìnnà sí irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀. Ara wọn ni àwọn tíí máa tọ ojúlé kiri, tí wọn máa ń ki àwọn aṣiwèrè obinrin mọ́lẹ̀, àwọn obinrin tí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ti wọ̀ lẹ́wù, tí wọn ń ṣe oríṣìíríṣìí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́. Àwọn obinrin wọnyi ń kẹ́kọ̀ọ́ nígbà gbogbo, sibẹ wọn kò lè ní ìmọ̀ òtítọ́. Bí Janesi ati Jamberesi ti tako Mose, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkunrin wọnyi tako òtítọ́. Orí irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀ ti kú, a sì ti ṣá wọn tì ní ti igbagbọ. Ṣugbọn wọn kò lè máa bá irú ìwà bẹ́ẹ̀ lọ pẹ́ títí. Nítorí pé ìwà wèrè wọn yóo hàn kedere sí gbogbo eniyan, gẹ́gẹ́ bí ti Janesi ati Jamberesi ti hàn. Ṣugbọn ìwọ ní tìrẹ, o ti tẹ̀lé ẹ̀kọ́ mi, ati ọ̀nà ìgbé-ayé mi, ète mi, ati igbagbọ mi, sùúrù mi, ìfẹ́ mi ati ìfaradà mi, ninu inúnibíni, ninu irú ìyà tí ó bá mi ní Antioku, ní Ikoniomu, ní Listira, ati oríṣìíríṣìí inúnibíni tí mo faradà. Oluwa ni ó yọ mí ninu gbogbo wọn. Wọn yóo ṣe inúnibíni sí gbogbo ẹni tí ó bá fẹ́ gbé ìgbé-ayé olùfọkànsìn gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ. Inúnibíni níláti dé sí wọn. Ṣugbọn yóo túbọ̀ máa burú sí i ni fún àwọn eniyan burúkú ati àwọn ẹlẹ́tàn: wọn yóo máa tan eniyan jẹ, eniyan yóo sì máa tan àwọn náà jẹ. Ṣugbọn, ìwọ ní tìrẹ, dúró gbọningbọnin ninu àwọn ohun tí o ti kọ́, tí ó sì dá ọ lójú. Ranti ọ̀dọ̀ àwọn ẹni tí o ti kọ́ wọn. Nítorí láti ìgbà tí o ti wà ní ọmọde ni o ti mọ Ìwé Mímọ́, tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n, tí o fi lè ní ìgbàlà nípa igbagbọ ninu Kristi Jesu. Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni ó ní ìmísí Ọlọrun, ó sì wúlò fún ẹ̀kọ́, fún ìbáwí, fún ìtọ́nisọ́nà, fún ìlànà nípa ìwà òdodo, kí eniyan Ọlọrun lè jẹ́ ẹni tí ó pé, tí ó múra sílẹ̀ láti ṣe gbogbo iṣẹ́ rere. Mò ń kìlọ̀ fún ọ níwájú Ọlọrun ati Kristi Jesu, tí ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ àwọn alààyè ati àwọn òkú; mò ń kì ọ́ nílọ̀ nítorí ìfarahàn rẹ̀ ati ìjọba rẹ̀. Waasu ọ̀rọ̀ náà. Tẹnumọ́ ọn ní àkókò tí ó wọ̀ ati àkókò tí kò wọ̀. Máa báni wí. Máa gbani ní ìyànjú. Máa gbani ní ìmọ̀ràn, pẹlu ọpọlọpọ sùúrù tí ó yẹ kí ẹni tí yóo bá kọ́ eniyan lẹ́kọ̀ọ́ dáradára ní. Àkókò ń bọ̀ tí àwọn eniyan kò ní fẹ́ fetí sí ẹ̀kọ́ tí ó yè. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara wọn ni wọn yóo tẹ̀lé, tí wọn yóo kó àwọn olùkọ́ tira, tí wọn yóo máa sọ ohun tí wọn máa ń fẹ́ gbọ́ fún wọn. Wọn óo di etí wọn sí òtítọ́; ìtàn àhesọ ti ara wọn ni wọn yóo máa gbọ́. Ṣugbọn, ìwọ ní tìrẹ, fi ara balẹ̀ ninu ohun gbogbo. Farada ìṣòro. Ṣe iṣẹ́ ìyìn rere. Má fi ohunkohun sílẹ̀ láì ṣe ninu iṣẹ́ iranṣẹ rẹ. Ní tèmi, a ti fi mí rúbọ ná. Àkókò ati fi ayé sílẹ̀ mi fẹ́rẹ̀ tó. Mo ti ja ìjà rere. Mo ti dé òpin iré ìje náà. Nisinsinyii adé òdodo náà wà nílẹ̀ fún mi, tí Oluwa onídàájọ́ òdodo yóo fún mi ní ọjọ́ náà. Èmi nìkan kọ́ ni yóo sì fún, yóo fún gbogbo àwọn tí wọn ń fi tìfẹ́tìfẹ́ retí ìfarahàn rẹ̀. Sa gbogbo ipá rẹ láti tètè wá sọ́dọ̀ mi. Demasi ti fi mí sílẹ̀ nítorí ó fẹ́ràn nǹkan ayé yìí. Ó ti lọ sí Tẹsalonika. Kirẹsẹnsi ti lọ sí Galatia. Titu ti lọ sí Dalimatia. Luku nìkan náà ni ó kù lọ́dọ̀ mi. Mú Maku lọ́wọ́ bí o bá ń bọ̀ nítorí ó wúlò fún mi bí iranṣẹ. Mo ti rán Tukikọsi lọ sí Efesu. Nígbà tí o bá ń bọ̀, bá mi mú agbádá tí mo fi sọ́dọ̀ Kapu ní Tiroasi bọ̀. Bá mi mú àwọn ìwé mi náà bọ̀, pataki jùlọ àwọn ìwé aláwọ mi. Alẹkisanderu, alágbẹ̀dẹ bàbà fi ojú mi rí nǹkan! Kí Oluwa san ẹ̀san fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀. Kí ìwọ náà ṣọ́ra lọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí títa ni ó ń tako àwọn ohun tí à ń sọ. Nígbà tí mo níláti jà fún ara mi ní ẹẹkinni, kò sí ẹni tí ó yọjú láti gbèjà mi: gbogbo wọn ni wọ́n fi mí sílẹ̀. Kí Ọlọrun má kà á sí wọn lọ́rùn. Ṣugbọn Oluwa dúró tì mí, ó fún mi lágbára tí mo fi waasu ìyìn rere lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, tí gbogbo àwọn tí kì í ṣe Juu fi gbọ́. Bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe bọ́ lẹ́nu kinniun. Oluwa yóo yọ mí kúrò ninu iṣẹ́ burúkú gbogbo, yóo sì gbà mí sinu ìjọba rẹ̀ ní ọ̀run. Tirẹ̀ ni ògo lae ati laelae. Amin. Kí Pirisila ati Akuila ati ìdílé Onesiforosi. Erastu ti dúró ní Kọrinti. Mo fi Tirofimọsi sílẹ̀ ní Miletu pẹlu àìlera. Sa ipá rẹ láti wá kí ó tó di àkókò òtútù. Yubulọsi kí ọ, ati Pudẹsi, Linọsi, Kilaudia ati gbogbo àwọn arakunrin. Kí Oluwa wà pẹlu ẹ̀mí rẹ. Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹlu gbogbo yín. Èmi Paulu, ẹrú Ọlọrun, ati aposteli Jesu Kristi, ni mò ń kọ ìwé yìí. Oluwa yàn mí láti jẹ́ kí àwọn àyànfẹ́ Ọlọrun lè ní igbagbọ ati ìmọ̀ òtítọ́ ti ẹ̀sìn, ati ìrètí ìyè ainipẹkun, tí Ọlọrun tí kì í purọ́ ti ṣèlérí láti ayérayé. Ó ti fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ hàn ní àkókò tí ó wọ̀ fún un ninu iwaasu tí ó ti fi lé mi lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ìlànà Ọlọrun Olùgbàlà wa. Mò ń kọ ìwé yìí sí Titu, ọmọ mi tòótọ́ ninu ẹ̀sìn igbagbọ kan náà. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba, ati Kristi Jesu Olùgbàlà wa, wà pẹlu rẹ̀. Ìdí tí mo ṣe fi ọ́ sílẹ̀ ní Kirete ni pé kí o ṣe àtúnṣe àwọn ohun tí ó kù tí kò dára tó, kí o sì yan àwọn àgbà lórí ìjọ ní gbogbo ìlú, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe ìlànà fún ọ. Ẹni tí ó bá jẹ́ aláìlẹ́gàn, tí ó ní ẹyọ iyawo kan, tí àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ́ onigbagbọ, tí ẹnìkan kò lè fi ẹ̀sùn kàn pé ó ń hùwà wọ̀bìà tabi pé ó jẹ́ alágídí. Nítorí alabojuto ìjọ níláti jẹ́ ẹni tí kò lẹ́gàn gẹ́gẹ́ bí ìríjú Ọlọrun. Kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí yóo máa ṣe ti inú ara rẹ̀, tabi kí ó jẹ́ onínúfùfù. Kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí ó fẹ́ràn ìjà, tabi ẹni tí ó ní ìwọ̀ra nípa ọ̀rọ̀ owó. Ó yẹ kí ó jẹ́ ẹni tí ó fẹ́ràn ati máa ṣe àlejò, tí ó sì fẹ́ ohun rere, ó yẹ kí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n, olódodo, olùfọkànsìn, ẹni tí ó ń kó ara rẹ̀ níjàánu. Kí ó di ọ̀rọ̀ tòótọ́ tí a ti fi kọ́ ọ mú ṣinṣin, kí ó baà lè ní ọ̀rọ̀ ìwúrí nípa ẹ̀kọ́ tí ó yè, kí ó sì lè bá àwọn alátakò wí. Nítorí àwọn alágídí pọ̀, tí wọn ń sọ̀rọ̀ asán, àwọn ẹlẹ́tàn, pàápàá jùlọ lára àwọn ọ̀kọlà. Dandan ni kí o pa wọ́n lẹ́nu mọ́, nítorí pé wọ́n ń da odidi agbo-ilé rú, wọ́n sì ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ tí kò tọ́ nítorí èrè tí kò yẹ. Ẹnìkan ninu wọn tí ó jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn wolii wọn sọ pé, “Òpùrọ́ paraku ni àwọn ará Kirete, ẹhànnà, ẹranko, ọ̀lẹ, alájẹkì.” Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí. Nítorí náà má gbojú fún wọn, bá wọn wí kí wọ́n lè ní igbagbọ tí ó pé. *** Kí wọn má máa lo àkókò wọn lórí ìtàn àròsọ àwọn Juu ati ìlànà àwọn eniyan tí wọ́n ti yapa kúrò lọ́nà òtítọ́. Gbogbo nǹkan ni ó mọ́ fún àwọn ẹni mímọ́, ṣugbọn kò sí nǹkankan tí ó mọ́ fún àwọn alaigbagbọ tí èrò wọn ti wọ́, nítorí èrò wọn ati ẹ̀rí ọkàn wọn ti wọ́. Wọ́n ń fi ẹnu jẹ́wọ́ pé àwọn mọ Ọlọrun, ṣugbọn wọ́n ń sẹ́ ẹ ninu ìwà wọn. Wọ́n jẹ́ ẹlẹ́gbin ati aláìgbọràn, wọn kò yẹ fún iṣẹ́ rere kan. Ní tìrẹ, àwọn ohun tí ó bá ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro mu ni kí ó máa ti ẹnu rẹ jáde. Àwọn àgbà ọkunrin níláti jẹ́ ẹni tí ó ń ṣe pẹ̀lẹ́, ẹni ọ̀wọ̀, ọlọ́gbọ́n, tí ó jinná ninu igbagbọ, ninu ìfẹ́ ati ninu ìfaradà. Bákan náà, àwọn àgbà obinrin níláti jẹ́ ẹni tí gbogbo ìgbé-ayé wọn bá ti ìsìn Ọlọrun mu. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ onísọkúsọ tabi ẹrú ọtí. Wọ́n níláti máa kọ́ni ní ohun rere. Kí wọn máa fi òye kọ́ àwọn ọdọmọbinrin wọn láti fẹ́ràn ọkọ wọn ati ọmọ wọn. Kí wọn máa fara balẹ̀, kí wọn sì fara mọ́ ọkọ wọn nìkan. Kí wọn má ya ọ̀lẹ ninu iṣẹ́ ilé, kí wọn sì jẹ́ onínú rere. Kí wọn máa gbọ́ràn sí ọkọ wọn lẹ́nu, kí ẹnikẹ́ni má baà lè sọ ìsọkúsọ sí ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Bákan náà, máa gba àwọn ọdọmọkunrin níyànjú láti fara balẹ̀. Kí o ṣe ara rẹ ní àpẹẹrẹ rere ní gbogbo ọ̀nà. Ninu ẹ̀kọ́ tí ò ń kọ́ àwọn eniyan, kí wọn rí òtítọ́ ninu rẹ, kí wọn sì rí ìwà àgbà lọ́wọ́ rẹ. Kí gbolohun ẹnu rẹ jẹ́ ti ọmọlúwàbí, tí ẹnìkan kò ní lè fi bá ọ wí. Èyí yóo mú ìtìjú bá ẹni tí ó bá fẹ́ ṣe alátakò nígbà tí kò bá rí ohun burúkú kan sọ nípa wa. Kí àwọn ẹrú fi ara wọn sí abẹ́ àṣẹ ọ̀gá wọn ninu ohun gbogbo. Kí wọn máa ṣe nǹkan tí yóo tẹ́ wọn lọ́rùn, kí wọn má máa fún wọn lésì. Kí wọn má máa ja ọ̀gá wọn lólè. Ṣugbọn kí wọn jẹ́ olóòótọ́ ati ẹni tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ní ọ̀nà gbogbo. Báyìí ni wọn yóo fi ṣe ẹ̀kọ́ Ọlọrun Olùgbàlà wa lọ́ṣọ̀ọ́ ninu ohun gbogbo. Nítorí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun ti farahàn fún ìgbàlà gbogbo eniyan. Ó ń tọ́ wa sọ́nà pé kí á kọ ìwà aibikita fún Ọlọrun ati ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ayé sílẹ̀, kí á máa farabalẹ̀. Kí á máa gbé ìgbé-ayé òdodo, kí á sì jẹ́ olùfọkànsìn ní ayé yìí. Kí á máa dúró de ibukun tí à ń retí, ati ìfarahàn ògo Ọlọrun ẹni ńlá, ati ti Olùgbàlà wa Jesu Kristi, ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún wa, láti rà wá pada kúrò ninu gbogbo agbára ẹ̀ṣẹ̀, ati láti wẹ̀ wá mọ́ láti fi wá ṣe ẹni tirẹ̀ tí yóo máa làkàkà láti ṣe iṣẹ́ rere. Báyìí ni kí o máa wí fún wọn, kí o máa fi gbà wọ́n níyànjú kí o sì máa bá wọn wí nígbà gbogbo pẹlu àṣẹ. Má gbà fún ẹnikẹ́ni láti fojú tẹmbẹlu rẹ. Máa rán wọn létí kí wọn máa tẹríba fún ìjọba ati àwọn aláṣẹ, kí wọn máa gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu, kí wọn sì múra láti máa ṣe iṣẹ́ rere gbogbo. Kí wọn má sọ ìsọkúsọ sí ẹnikẹ́ni. Kí wọn kórìíra ìjà. Kí wọn ní ìfaradà. Kí wọ́n máa fi ìrẹ̀lẹ̀ bá gbogbo eniyan lò. Nítorí nígbà kan rí, àwa náà ń ṣe wérewère, à ń ṣe àìgbọràn, ayé ń tàn wá jẹ, a jẹ́ ẹrú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, a sì ń jẹ ayé ìjẹkújẹ ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà. À ń hùwà ìkà ati ìlara. A jẹ́ ohun ìríra fún àwọn eniyan. Àwa náà sì kórìíra ọmọnikeji wa. Ṣugbọn nígbà tí Ọlọrun fi inú rere ati ìfẹ́ rẹ̀ sí àwa eniyan hàn, ó gbà wá là; kì í ṣe nítorí iṣẹ́ rere kan tí a ṣe, ṣugbọn nítorí àánú rẹ̀ ni ó fi gbà wá là, nípa ìwẹ̀mọ́ pẹlu omi tí ó fi tún wa bí, ati Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó fi sọ wá di ẹni titun. Ó da Ẹ̀mí yìí lé wa lórí lọpọlọpọ láti ọwọ́ Jesu Kristi Olùgbàlà wa. Ó dá wa láre nípa oore-ọ̀fẹ́ kan náà, tí a fi ní ìrètí láti di ajogún ìyè ainipẹkun. Ọ̀rọ̀ tí ó dájú ni ọ̀rọ̀ yìí. Mo fẹ́ kí o tẹnumọ́ àwọn nǹkan wọnyi, kí àwọn tí ó ti gba Ọlọrun gbọ́ lè fi ọkàn sí i láti máa ṣe iṣẹ́ tí ó dára. Irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ dára, wọ́n sì ń ṣe eniyan ní anfaani. Ṣugbọn yẹra fún iyàn jíjà lórí ọ̀rọ̀ wèrè ati ìtàn ìrandíran, ati ìjà, ati àríyànjiyàn lórí ọ̀rọ̀ òfin. Nítorí wọn kò ṣe eniyan ní anfaani, wọn kò sì wúlò rárá. Bí o bá ti kìlọ̀ fún adíjàsílẹ̀ lẹ́ẹ̀kan tabi lẹẹmeji, tí kò gbọ́, yẹra fún un. Mọ̀ pé ọkàn irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti wọ́, ó ń dá ẹ̀ṣẹ̀, ó sì ń dá ara rẹ̀ lẹ́bi. Nígbà tí mo bá rán Atemasi tabi Tukikọsi sí ọ, sa ipá rẹ láti wá sọ́dọ̀ mi ní ìlú Nikopoli, nítorí níbẹ̀ ni mo pinnu láti wà ní àkókò òtútù. Sa gbogbo ipá rẹ láti ran Senasi, lọ́yà, ati Apolo lọ́wọ́ kí wọn lè bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn, kí o sì rí i pé gbogbo ohun tí wọ́n nílò tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́. Àwọn eniyan wa níláti kọ́ láti ṣe iṣẹ́ rere kí wọ́n lè gbọ́ bùkátà wọn; wọn kò gbọdọ̀ jókòó tẹtẹrẹ láìṣe nǹkankan. Gbogbo àwọn ẹni tí ó wà lọ́dọ̀ mi ní kí n kí ọ. Bá wa kí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ wa ninu igbagbọ. Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹlu gbogbo yín. Èmi Paulu, ẹlẹ́wọ̀n nítorí ti Kristi Jesu, ati Timoti, arakunrin wa, ni à ń kọ ìwé yìí sí Filemoni, àyànfẹ́ wa ati alábàáṣiṣẹ́ wa, ati sí Afia, arabinrin wa ati sí Akipu: ọmọ-ogun ẹlẹgbẹ́ wa fún Kristi, ati sí ìjọ tí ó wà ninu ilé rẹ̀. Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹlu yín ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba wa, ati Oluwa Jesu Kristi. Nígbà gbogbo tí mo bá ń ranti rẹ ninu adura ni mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun. Mò ń gbọ́ ìròyìn ìfẹ́ ati igbagbọ tí o ní sí Oluwa Jesu, ati sí gbogbo àwọn onigbagbọ. Adura mi ni pé kí àjọṣepọ̀ tàwa-tìrẹ ninu igbagbọ lè ṣiṣẹ́, láti mú kí òye rẹ pọ̀ sí i nípa gbogbo ohun rere tí a ní ninu Kristi. Nítorí mo láyọ̀ pupọ, mo sì ní ìwúrí lọpọlọpọ nípa ìfẹ́ rẹ. Nítorí ohun tí ò ń ṣe ti tu àwọn onigbagbọ lára, arakunrin mi. Nítorí náà, bí mo tilẹ̀ ní ìgboyà pupọ ninu Kristi láti pàṣẹ ohun tí ó yẹ fún ọ, ṣugbọn nítorí ìfẹ́ tí ó wà láàrin wa, ẹ̀bẹ̀ ni n óo kúkú bẹ̀. Èmi Paulu, ikọ̀ Kristi, tí mo di ẹlẹ́wọ̀n nisinsinyii nítorí ti Kristi Jesu, mò ń bẹ̀ ọ́ nítorí ti ọmọ mi, Onisimu, ọmọ tí mo bí ninu ẹ̀wọ̀n. Nígbà kan rí kò wúlò fún ọ. Ṣugbọn nisinsinyii ó wúlò fún ọ ati fún mi. Òun ni mò ń rán pada sí ọ. Ó wá dàbí ẹni pé mò ń fi ọkàn èmi pàápàá ranṣẹ sí ọ. Ǹ bá dá a dúró, kó máa wà lọ́dọ̀ mi, kí ó lè máa ṣe ìrànlọ́wọ́ fún mi dípò rẹ lákòókò tí mo wà ninu ẹ̀wọ̀n nítorí iṣẹ́ ìyìn rere. Ṣugbọn n kò fẹ́ dá nǹkankan ṣe láìjẹ́ pé o lọ́wọ́ sí i, n kò fẹ́ kí ó jẹ́ pé túlààsì ni oore tí mo fẹ́ kí o ṣe. Inú rẹ ni mo fẹ́ kí ó ti wá. Bóyá ìdí nìyí tí ó fi sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ fún ìgbà díẹ̀, kí o lè jèrè rẹ̀ ní gbogbo ìgbà; kì í tún ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹrú mọ́, ṣugbọn ní ipò tí ó ga ju ti ẹrú lọ, bí àyànfẹ́ arakunrin, tí ó ṣọ̀wọ́n fún mi, ṣugbọn tí ó ṣọ̀wọ́n fún ọ jù mí lọ, gẹ́gẹ́ bí eniyan sí eniyan ati gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ. Nítorí náà bí o bá kà mí sí ẹni tí a jọ gba nǹkankan náà gbọ́, kí o gbà á pada tọwọ́-tẹsẹ̀ bí ẹni pé èmi alára ni o gbà. Ohunkohun tí ó bá ti ṣe sí ọ láìdára, tabi ohun tí ó bá jẹ ọ́, èmi ni kí o kà á sí lọ́rùn. Èmi, Paulu, ni mo fi ọwọ́ ara mi kọ ọ́ pé, n óo san án pada fún ọ. Kò tún nílò kí n sọ fún ọ pé ìwọ fúnrarẹ, o jẹ mí ní gbèsè ara rẹ. Arakunrin mi, mo fẹ́ kí o yọ̀ǹda ọ̀rọ̀ yìí fún mi nítorí Oluwa. Fi ọkàn mi balẹ̀ ninu Kristi. Pẹlu ìdánilójú pé o óo ṣe bí mo ti wí ni mo fi kọ ìwé yìí sí ọ; mo sì mọ̀ pé o óo tilẹ̀ ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó ku nǹkankan: Tọ́jú ààyè sílẹ̀ dè mí, nítorí mo ní ìrètí pé, nípa adura yín, Ọlọrun yóo jẹ́ kí wọ́n dá mi sílẹ̀ fun yín. Epafirasi, ẹlẹ́wọ̀n ẹlẹgbẹ́ mi nítorí ti Kristi Jesu, kí ọ. Bẹ́ẹ̀ ni Maku, ati Arisitakọsi, ati Demasi ati Luku, àwọn alábàáṣiṣẹ́ mi. Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa Jesu Kristi kí ó wà pẹlu ẹ̀mí yín. Ní ìgbà àtijọ́, oríṣìíríṣìí ọ̀nà ni Ọlọrun fi ń bá àwọn baba wa sọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wolii rẹ̀. Ní àkókò ìkẹyìn yìí, ó wá bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀, ẹni tí ó fi ṣe àrólé ohun gbogbo, nípasẹ̀ ẹni tí ó dá ayé. Ọmọ yìí jẹ́ ẹni tí ògo Ọlọrun hàn lára rẹ̀, ó sì jẹ́ àwòrán bí Ọlọrun ti rí gan-an. Òun ni ó mú kí gbogbo nǹkan dúró nípa agbára ọ̀rọ̀ rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó ti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ eniyan nù tán, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọ̀gá Ògo ní ibi tí ó ga jùlọ. Ó ní ipò tí ó ga ju ti àwọn angẹli lọ, gẹ́gẹ́ bí ó ti ní orúkọ tí ó ju tiwọn lọ. Nítorí èwo ninu àwọn angẹli ni ó fi ìgbà kan sọ fún pé, “Ìwọ ni ọmọ mi, lónìí ni mo bí ọ?” Tabi tí ó sọ fún pé, “Èmi yóo jẹ́ baba fún un, òun náà yóo sì jẹ́ ọmọ fún mi?” Ṣugbọn nígbà tí ó mú àkọ́bí rẹ̀ wọ inú ayé, ohun tí ó sọ ni pé, “Kí gbogbo àwọn angẹli Ọlọrun foríbalẹ̀ fún un.” Ohun tí ó sọ nípa àwọn angẹli ni pé, “Ẹni tí ó ṣe àwọn angẹli rẹ̀ ní ẹ̀fúùfù, tí ó ṣe àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ iná.” Ṣugbọn ohun tí ó sọ fún Ọmọ náà ni pé, “Ìfẹ́ rẹ wà títí laelae, Ọlọrun, ọ̀pá òtítọ́ ni ọ̀pá ìjọba rẹ. O fẹ́ràn òdodo, o kórìíra ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí èyí, Ọlọrun, àní Ọlọrun rẹ, fi òróró yàn ọ́ láti gbé ọ ga ju àwọn ẹgbẹ́ rẹ lọ.” Ó tún sọ pé, “O ti wà láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé, Oluwa, ìwọ ni o fi ìpìlẹ̀ ayé lélẹ̀. Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ni àwọn ọ̀run. Wọn óo parẹ́ ṣugbọn ìwọ óo wà títí. Gbogbo wọn óo gbó bí aṣọ. Gẹ́gẹ́ bí eniyan tií ká aṣọ ni ìwọ óo ká wọn. Gẹ́gẹ́ bí aṣọ, a óo pààrọ̀ wọn. Ṣugbọn ní tìrẹ, bákan náà ni o wà. Kò sí òpin sí iye ọdún rẹ.” Èwo ninu àwọn angẹli ni ó fi ìgbà kan sọ fún pé, “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí n óo fi ṣe àwọn ọ̀tá rẹ ní àpótí ìtìsẹ̀ rẹ?” Ṣebí ẹ̀mí tí ó jẹ́ iranṣẹ ni gbogbo àwọn angẹli. A rán wọn láti ṣiṣẹ́ nítorí àwọn tí yóo jogún ìgbàlà. Nítorí náà, ó yẹ kí á túbọ̀ ṣe akiyesi àwọn ohun tí à ń gbọ́, kí á má baà gbá wa lọ bí ìgbà tí odò gbá nǹkan lọ. Nítorí bí ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu àwọn angẹli sọ bá fẹsẹ̀ múlẹ̀, tí gbogbo ìwà àìṣedéédé ati ìwà àìgbọràn bá gba ìbáwí tí ó tọ́ sí wọn, báwo ni a óo ti ṣe sá àsálà, tí a bá kọ etí-ikún sí ìgbàlà tí ó tóbi tó báyìí? Oluwa fúnrarẹ̀ ni ó kọ́kọ́ kéde ìgbàlà yìí ní ìbẹ̀rẹ̀. Àwọn tí wọ́n gbọ́ ni wọ́n fún wa ní ìdánilójú pé bẹ́ẹ̀ ni ó rí. Ọlọrun pàápàá tún jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ náà nípa àwọn àmì ati iṣẹ́ ìyanu ati oríṣìíríṣìí iṣẹ́ tí ó ju agbára ẹ̀dá lọ, tí ó ṣe nípa Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó pín gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀. Nítorí kì í ṣe àwọn angẹli ni ó fún ní àṣẹ láti ṣe àkóso ayé tí ń bọ̀, èyí tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó wà ní àkọsílẹ̀ níbi tí ẹnìkan ti sọ pé, “Kí ni eniyan, tí o fi ń ranti rẹ̀, tabi ọmọ eniyan tí o fi ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀? O dá a, ipò rẹ̀ rẹlẹ̀ díẹ̀ ju ti àwọn angẹli lọ fún àkókò díẹ̀. O sì fi ògo ati ọlá dé e ládé. O fi gbogbo nǹkan sí ìkáwọ́ rẹ̀.” Nítorí pé ó fi gbogbo nǹkan wọnyi sí ìkáwọ́ rẹ̀, kò ku nǹkankan tí kò sí ní ìkáwọ́ rẹ̀. Ṣugbọn nígbà náà, a kò ì tíì rí i, pé gbogbo nǹkan ni ó ti wà ní ìkáwọ́ rẹ̀. Ṣugbọn a rí Jesu, tí Ọlọrun fi sí ipò tí ó rẹlẹ̀ díẹ̀ ju ti àwọn angẹli fún àkókò díẹ̀. Òun ni ó jẹ oró ikú, tí Ọlọrun tún wá fi ògo ati ọlá dé e ládé. Nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun ó kú fún gbogbo eniyan. Nítorí pé kí Ọlọrun tí ó dá gbogbo nǹkan, tí ó sì mú kí gbogbo nǹkan wà, lè mú ọpọlọpọ wá sí inú ògo, ó tọ́ kí ó ṣe aṣaaju tí yóo la ọ̀nà ìgbàlà sílẹ̀ fún wọn nípa ìyà jíjẹ. Nítorí ọ̀kan ni ẹni tí ó ń ya eniyan sí mímọ́ ati àwọn eniyan tí ó ń yà sí mímọ́ jẹ́, nítorí náà ni Jesu kò fi tijú láti pè wọ́n ní arakunrin rẹ̀. Ó ní, “Èmi óo pe orúkọ rẹ ní gbangba fún àwọn arakunrin mi. Ní ààrin àwùjọ ni n óo yìn ọ́.” Ó tún sọ pé, “Èmi ní tèmi, èmi óo gbẹ́kẹ̀lé e.” Ati pé, “Èmi nìyí ati àwọn ọmọ tí Ọlọrun fi fún mi.” Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọmọ jẹ́ ẹlẹ́ran-ara ati ẹlẹ́jẹ̀, Jesu pàápàá di ẹlẹ́ran-ara ati ẹlẹ́jẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi wọn, kí ó lè ti ipasẹ̀ ikú rẹ̀ sọ agbára Satani tí ó ní ikú ní ìkáwọ́ di asán. Ó wá dá àwọn tí ẹ̀rù ikú ti sọ di ẹrú ninu gbogbo ìgbé-ayé wọn sílẹ̀. Nítorí ó dájú pé, kì í ṣe àwọn angẹli ni ó wá ṣe ìrànlọ́wọ́ fún bíkòṣe àwọn ọmọ Abrahamu. Nítorí náà, dandan ni kí òun alára jọ àwọn arakunrin rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà, kí ó lè jẹ́ Olórí Alufaa tí ó láàánú, tí ó sì ṣe é gbójú lé nígbà tí ó bá ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ níwájú Ọlọrun fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan. Nítorí níwọ̀n ìgbà tí òun alára ti jìyà, ó lè ran àwọn tí wọ́n wà ninu ìdánwò lọ́wọ́. Nítorí náà, ẹ̀yin ará ninu Oluwa, tí a jọ ní ìpín ninu ìpè tí ó ti ọ̀run wá, ẹ ṣe akiyesi Jesu, tíí ṣe òjíṣẹ́ ati Olórí Alufaa ìjẹ́wọ́ igbagbọ wa. Ẹ rí i pé ó ṣe olóòótọ́ sí Ọlọrun tí ó yàn án gẹ́gẹ́ bí Mose ti ṣe oloòótọ́ ninu gbogbo ìdílé Ọlọrun. Nítorí bí ẹni tí ó kọ́ ilé ti ní ọlá ju ilé tí ó kọ́ lọ, bẹ́ẹ̀ ni Jesu yìí ní ọlá ju Mose lọ. Nítorí kò sí ilé kan tí kò jẹ́ pé eniyan ni ó kọ́ ọ. Ṣugbọn Ọlọrun ni ó ṣe ohun gbogbo. Mose ṣe olóòótọ́ ninu gbogbo ìdílé Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí iranṣẹ. A rán an láti jẹ́rìí sí àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọrun yóo fi fún un láti sọ ni. Ṣugbọn Kristi ṣe olóòótọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ninu ìdílé rẹ̀. Àwa gan-an ni ìdílé rẹ̀ náà, bí a bá dúró pẹlu ìgboyà tí à ń ṣògo lórí ìrètí wa. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti wí, “Lónìí, bí ẹ bá gbọ́ ohùn rẹ̀, ẹ má ṣe agídí, gẹ́gẹ́ bíi ti àkókò ìṣọ̀tẹ̀, ní àkókò ìdánwò ninu aṣálẹ̀, nígbà tí àwọn baba-ńlá yín dán mi wò, tí wọ́n fi rí iṣẹ́ mi fún ogoji ọdún. Nítorí náà, mo bínú sí ìran wọn. Mo ní, ‘Nígbà gbogbo ni wọ́n máa ń ṣìnà ní ọkàn wọn. Iṣẹ́ mi kò yé wọn.’ Ni mo bá búra pẹlu ibinu, pé wọn kò ní dé ibi ìsinmi mi.” Ẹ kíyèsára, ará, kí ó má ṣe sí ẹnikẹ́ni ninu yín tí yóo ní inú burúkú tóbẹ́ẹ̀ ti kò ní ní igbagbọ, tí yóo wá pada kúrò lẹ́yìn Ọlọrun alààyè. Ṣugbọn ẹ máa gba ara yín níyànjú lojoojumọ níwọ̀n ìgbà tí ọ̀rọ̀ “Òní” tí Ìwé Mímọ́ sọ bá ti bá àwa náà wí, kí ẹ̀ṣẹ̀ má baà tan ẹnikẹ́ni lọ, kí ó sì mú kí ó ṣe agídí sí Ọlọrun. Nítorí a ti di àwọn tí ó ń bá Kristi kẹ́gbẹ́ bí a bá fi ọkàn tán an títí dé òpin gẹ́gẹ́ bí a ti fi ọkàn tán an ní ìbẹ̀rẹ̀ igbagbọ wa. Bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Lónìí, bí ẹ bá gbọ́ ohùn rẹ̀, ẹ má ṣe agídí gẹ́gẹ́ bíi ti àkókò ọ̀tẹ̀.” Mò ń bèèrè, àwọn ta ni ó gbọ́ tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀? Ṣebí gbogbo àwọn tí wọ́n bá Mose jáde kúrò ní Ijipti ni. Àwọn ta ni Ọlọrun bínú sí ní ogoji ọdún? Ṣebí àwọn tí ó ṣẹ̀ ni, tí òkú wọn wà káàkiri ní aṣálẹ̀. Àwọn ta ni ó búra pé wọn kò ní wọ inú ìsinmi òun? Ṣebí àwọn aláìgbọràn ni. A rí i pé wọn kò lè wọ inú ìsinmi yìí nítorí wọn kò gbàgbọ́. Nítorí náà níwọ̀n ìgbà tì ìlérí àtiwọ inú ìsinmi rẹ̀ tún wà, ẹ jẹ́ kí á ṣọ́ra gidigidi kí ẹnikẹ́ni ninu yín má baà kùnà láti wọ̀ ọ́. Nítorí àwa náà ti gbọ́ ìyìn rere bí àwọn tọ̀hún ti gbọ́. Ṣugbọn ọ̀rọ̀ tí àwọn gbọ́ kò ṣe wọ́n ní anfaani, nítorí wọn kò ní igbagbọ ninu ohun tí wọ́n gbọ́. Àwa tí a gbàgbọ́ ni a wọ inú ìsinmi náà. Nígbà tí Ọlọrun sọ pé, “Mo búra pẹlu ibinu pé, wọn kò ní wọ inú ìsinmi mi.” Ó sọ bẹ́ẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti parí iṣẹ́ rẹ̀ láti ìpìlẹ̀ ayé. Nítorí Ìwé Mímọ́ sọ níbìkan nípa ọjọ́ keje pé, “Ọlọrun sinmi ninu gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ní ọjọ́ keje.” Lẹ́ẹ̀kan sí i, ohun tí ó sọ ní ibí yìí ni pé, “Wọn kò ní wọ inú ìsinmi mi.” Nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ará àtijọ́ tí wọ́n gbọ́ ìyìn rere kò wọ inú ìsinmi náà nítorí àìgbọràn, nítorí náà ó ku àwọn kan tí wọn yóo wọ inú rẹ̀. Ọlọrun wá tún yan ọjọ́ mìíràn. Ninu ìwé Dafidi, tí ó kọ lẹ́yìn ọdún pupọ, ó sọ pé, “Lónìí”, níbi tí atọ́ka sí, tí ó kà báyìí pé, “Lónìí, bí ẹ bá gbọ́ ohùn rẹ̀, Ẹ má ṣe agídí.” Bí ó bá jẹ́ pé Joṣua fún wọn ní ìsinmi ni, Ọlọrun kò ní tún sọ nípa ọjọ́ mìíràn mọ́ lẹ́yìn ọjọ́ pupọ. Nítorí náà, ìsinmi ọjọ́ ìsinmi wà nílẹ̀ fún àwọn eniyan Ọlọrun. Nítorí ẹni tí ó bá wọ inú ìsinmi rẹ̀ ti sinmi ninu iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti sinmi ninu tirẹ̀. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á sa gbogbo ipá wa láti wọ inú ìsinmi náà, kí ẹnikẹ́ni má tẹ̀lé àpẹẹrẹ burúkú ati àìgbọràn bíi ti àwọn tí à ń sọ̀rọ̀ wọn. Nítorí pé ọ̀rọ̀ Ọlọrun wà láàyè, ó sì lágbára. Ó mú ju idà olójú meji lọ. Ó mú tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi lè gé ẹ̀mí kúrò lára ọkàn, ó sì lè rẹ́ mùdùnmúdùn kúrò lára àwọn oríkèé ara. Ó yára láti mọ ète ati èrò ọkàn eniyan. Kò sí ẹ̀dá kan tí ó lè fara pamọ́ níwájú rẹ̀. Gbogbo nǹkan ṣípayá kedere níwájú Ọlọrun, ẹni tí a óo jíyìn iṣẹ́ wa fún. Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí a ní Olórí Alufaa ńlá tí ó ti kọjá lọ sí ọ̀run tíí ṣe Jesu Ọmọ Ọlọrun, ẹ jẹ́ kí á di ohun ti a fi igbagbọ jẹ́wọ́ mú ṣinṣin. Nítorí Olórí Alufaa tí a ní kì í ṣe ẹni tí kò lè bá wa kẹ́dùn ninu àwọn àìlera wa. Ṣugbọn ó jẹ́ ẹni tí a ti dán wò ní gbogbo ọ̀nà bíi wa, ṣugbọn òun kò dẹ́ṣẹ̀. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á fi ìgboyà súnmọ́ ìtẹ́ oore-ọ̀fẹ́, kí á lè rí àánú gbà, ati nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, kí á lè rí ìrànlọ́wọ́ ní àkókò tí ó wọ̀. Nítorí ẹnikẹ́ni tí a bá yàn láàrin àwọn eniyan láti jẹ́ olórí alufaa, a yàn án bí aṣojú àwọn eniyan níwájú Ọlọrun, kí ó lè máa mú àwọn ọrẹ ati ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn wá siwaju Ọlọrun. Ó lè fi sùúrù bá àwọn tí wọ́n ṣìnà nítorí wọn kò gbọ́ lò, nítorí pé eniyan aláìlera ni òun náà. Nítorí èyí, bí ó ti ń rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan, bẹ́ẹ̀ ni yóo máa rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ ti òun alára. Kò sí ẹni tíí yan ara rẹ̀ sí ipò yìí. Ṣugbọn àwọn tí Ọlọrun bá pè ni à ń yàn, bíi Aaroni. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni, Kristi náà kò yan ògo yìí fúnrarẹ̀, láti jẹ́ olórí alufaa. Ọlọrun ni ó yàn án. Ọlọrun ni ó sọ fún un pé, “Ìwọ ni Ọmọ mi, lónìí ni mo bí ọ.” Bẹ́ẹ̀ náà ni ó sọ ní ibòmíràn pé, “Alufaa ni ọ́ títí laelae gẹ́gẹ́ bíi ti Mẹlikisẹdẹki.” Ní ìgbà ayé Jesu, pẹlu igbe ńlá ati ẹkún, ó fi adura ati ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ siwaju ẹni tí ó lè gbà á lọ́wọ́ ikú. Nítorí pé ó bọ̀wọ̀ fún Ọlọrun, adura rẹ̀ gbà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọmọ ni, ó kọ́ láti gbọ́ràn nípa ìyà tí ó jẹ. Nígbà tí a ti ṣe é ní àṣepé, ó wá di orísun ìgbàlà tí kò lópin fún gbogbo àwọn tí wọ́n bá gbà á gbọ́. Òun ni Ọlọrun pè ní olórí alufaa gẹ́gẹ́ bíi ti Mẹlikisẹdẹki. A ní ọ̀rọ̀ pupọ láti sọ fun yín nípa Mẹlikisẹdẹki yìí. Ọ̀rọ̀ náà ṣòro láti túmọ̀ nígbà tí ọkàn yín ti le báyìí. Nítorí ó ti yẹ kí ẹ di olùkọ́ni ní ọjọ́ tí ó ti pẹ́. Sibẹ ẹ tún wà ninu àwọn tí a óo máa kọ́ ní “A, B, D,” nípa nǹkan tí ó jẹ mọ́ ti Ọlọrun. Ẹ wà ninu àwọn tí a óo máa fi wàrà bọ́, ẹ kò ì tíì lè jẹ oúnjẹ gidi. Nítorí gbogbo àwọn tí wọ́n bá sì ń mu wàrà, kò tíì mọ ẹ̀kọ́ nípa òdodo, nítorí ọmọ-ọwọ́ ni irú wọn. Ṣugbọn oúnjẹ gidi ni àgbàlagbà máa ń jẹ, àwọn tí ìrírí wọn fún ọjọ́ pípẹ́ ti fún ní òye láti mọ ìyàtọ̀ láàrin nǹkan rere ati nǹkan burúkú. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á pa ẹ̀kọ́ alakọọbẹrẹ ti ìsìn igbagbọ tì, kí á tẹ̀síwájú láti kọ́ ẹ̀kọ́ tí ó jinlẹ̀. Kí á má tún máa fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ mọ́, ìpìlẹ̀ bí ẹ̀kọ́ nípa ìrònúpìwàdà kúrò ninu àwọn iṣẹ́ tí ó yọrí sí ikú, ẹ̀kọ́ nípa igbagbọ ninu Ọlọrun; ẹ̀kọ́ nípa ìrìbọmi, ìgbé-ọwọ́-lé eniyan lórí, ajinde kúrò ninu òkú, ati ìdájọ́ ìkẹyìn. Ẹ jẹ́ kí á tẹ̀síwájú nípa kíkọ́ ẹ̀kọ́ tí ó jinlẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni a óo sì ṣe, bí Ọlọrun bá fẹ́. Nítorí àwọn tí a bá ti là lójú, tí wọ́n ti tọ́wò ninu ẹ̀bùn tí ó ti ọ̀run wá, àwọn tí wọ́n ti ní ìpín ninu ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, tí wọ́n ti tọ́ ire tí ó wà ninu ọ̀rọ̀ Ọlọrun wò, ati agbára ayé tí ó ń bọ̀, tí wọ́n bá wá yipada kúrò ninu ìsìn igbagbọ, kò sí ohun tí a lè ṣe tí wọ́n fi lè tún ronupiwada mọ́, nítorí wọ́n ti tún fi ọwọ́ ara wọn kan Ọmọ Ọlọrun mọ́ agbelebu, wọ́n sọ ikú rẹ̀ di nǹkan àwàdà. Nítorí nígbà tí ilẹ̀ bá ń mu omi òjò tí ń rọ̀ sórí rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà, tí ó sì ń mú kí ohun ọ̀gbìn hù fún àwọn àgbẹ̀ tí ń roko níbẹ̀, ilẹ̀ náà ń gba ibukun Ọlọrun ni. Ṣugbọn bí ó bá ń hu ẹ̀gún ati igikígi, kò wúlò, kò sì ní pẹ́ tí Ọlọrun yóo fi fi í gégùn-ún. Ní ìkẹyìn, iná ni a óo dá sun ún. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń sọ̀rọ̀ báyìí, sibẹ ó dá wa lójú nípa tiyín, ẹ̀yin àyànfẹ́, pé ipò yín dára jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ ní ohun tí ó yẹ fún ìgbàlà. Nítorí Ọlọrun kì í ṣe alaiṣootọ, tí yóo fi gbàgbé iṣẹ́ yín ati ìfẹ́ yín tí ẹ fihàn sí orúkọ rẹ̀, nígbà tí ẹ ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún àwọn onigbagbọ, bí ẹ ti tún ń ṣe nisinsinyii. Ìfẹ́ ọkàn wa ni pé kí olukuluku yín fi ìtara kan náà hàn, tí ẹ fi lè ní ẹ̀kún ìrètí yín títí dé òpin; kí ẹ má jẹ́ òpè, ṣugbọn kí ẹ fara wé àwọn tí wọ́n fi igbagbọ ati sùúrù jogún àwọn ìlérí Ọlọrun. Nítorí nígbà tí Ọlọrun ṣe ìlérí fún Abrahamu, ara rẹ̀ ni ó fi búra nígbà tí kò sí ẹnìkan tí ó tóbi bíi rẹ̀ tí ìbá fi búra. Ó ní, “Ní ti ibukun, n óo bukun ọ. Ní ti kí eniyan pọ̀, n óo sọ ọ́ di pupọ.” Bẹ́ẹ̀ ni Abrahamu ṣe gba ìlérí náà pẹlu sùúrù. Ẹni tí ó bá juni lọ ni a fi í búra. Ọ̀rọ̀ tí eniyan bá sì ti búra lé lórí, kò sí àríyànjiyàn lórí rẹ̀ mọ́. Ní ọ̀nà kan náà, nígbà tí Ọlọrun fẹ́ fihàn gbangba fún àwọn ajogún ìlérí wí pé èrò òun kò yipada, ó ṣe ìlérí, ó sì fi ìbúra tì í. Èyí ni pé nípa ohun meji tí kò ṣe é yipada, tí Ọlọrun kò sì lè fi purọ́ ni àwa tí a sá di Ọlọrun fi lè ní ìwúrí pupọ láti di ìlérí tí ó wà níwájú wa mú. A di ìlérí náà mú. Ó dàbí ìdákọ̀ró fún ọkàn wa. Ìlérí yìí dájú, ó sì ṣe é gbẹ́kẹ̀lé. Ó ti wọ inú yàrá tí ó wà ninu, lẹ́yìn aṣọ ìkélé, níbi tí Jesu aṣiwaju wa ti wọ̀ lọ, tí ó di olórí alufaa títí lae gẹ́gẹ́ bíi Mẹlikisẹdẹki. Nítorí Mẹlikisẹdẹki yìí jẹ́ ọba Salẹmu ati alufaa Ọlọrun Ọ̀gá Ògo. Òun ni ó pàdé Abrahamu nígbà tí Abrahamu ń pada bọ̀ láti ojú-ogun lẹ́yìn tí ó bá ọba mẹrin jà, tí ó sì pa wọ́n ní ìpakúpa. Ó bá súre fún Abrahamu. Abrahamu fún un ní ìdámẹ́wàá gbogbo ìkógun. Ní àkọ́kọ́, ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀ ni “ọba òdodo.” Lẹ́yìn náà, ó tún jẹ́ ọba Salẹmu, èyí ni “ọba alaafia.” Kò sí àkọsílẹ̀ pé ó ní baba tabi ìyá; kò ní ìtàn ìdílé. Kò sí àkọsílẹ̀ ìbẹ̀rẹ̀ tabi òpin ìgbé-ayé rẹ̀. Ó jẹ́ àwòrán Ọmọ Ọlọrun. Ó jẹ́ alufaa nígbà gbogbo. Ẹ kò rí bí ọkunrin yìí ti jẹ́ eniyan pataki tó, tí Abrahamu baba-ńlá wa fi fún un ní ìdámẹ́wàá àwọn nǹkan àṣàyàn ninu ìkógun rẹ̀. Àwọn ọmọ Lefi ni wọ́n ní àṣẹ láti gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn eniyan gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin. Wọ́n ń gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn eniyan wọn tí wọ́n jẹ́ ìran Abrahamu. Ṣugbọn Mẹlikisẹdẹki tí kì í ṣe ìran Abrahamu gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì súre fún Abrahamu tí ó rí àwọn ìlérí Ọlọrun gbà. Láìṣe àní-àní, ẹni tí ó bá tóbi ju eniyan lọ níí súre fún un. Ati pé, àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń gba ìdámẹ́wàá, ẹni tí yóo kú ni wọ́n. Ṣugbọn Ìwé Mímọ́ sọ nípa Mẹlikisẹdẹki pé ó wà láàyè. A lè sọ pé nígbà tí Abrahamu san ìdámẹ́wàá, Lefi tí ń gba ìdámẹ́wàá náà san ìdámẹ́wàá, nítorí a lè sọ pé ó wà ní ara Abrahamu baba-ńlá rẹ̀ nígbà tí Mẹlikisẹdẹki pàdé rẹ̀. Nítorí náà, bí ó bá jẹ́ pé ètò iṣẹ́ alufaa ti ìdílé Lefi kò ní àbùkù, tí ó sì jẹ́ pé nípa rẹ̀ ni àwọn eniyan fi gba òfin, kí ló dé tí a fi tún ṣe ètò alufaa ní ìgbésẹ̀ Mẹlikisẹdẹki, tí kò fi jẹ́ ti Aaroni? Nítorí bí a bá yí ètò iṣẹ́ alufaa pada, ó níláti jẹ́ pé a yí òfin náà pada. Ẹni tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí wá láti inú ẹ̀yà mìíràn. Ninu ẹ̀yà yìí ẹ̀wẹ̀, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó ní nǹkankan ṣe pẹlu ẹbọ rírú. Nítorí ó hàn gbangba pé láti inú ẹ̀yà Juda ni Oluwa wa ti wá. Mose kò sì sọ ohunkohun tí ó jẹ mọ́ iṣẹ́ alufaa nípa ẹ̀yà yìí. Ohun tí à ń sọ hàn kedere nígbà tí a rí i pé a yan alufaa mìíràn gẹ́gẹ́ bí àwòrán Mẹlikisẹdẹki, ẹni tí ó di alufaa nípa agbára ìyà tí kò lópin, tí kì í ṣe nípa ìlànà àṣẹ tí a ti ọwọ́ eniyan ṣe ètò. Nítorí a rí ẹ̀rí níbìkan pé, “Ìwọ yóo jẹ́ alufaa títí lae, gẹ́gẹ́ bíi ti Mẹlikisẹdẹki.” A pa àṣẹ ti àkọ́kọ́ tì nítorí kò lágbára, kò sì wúlò. Nítorí kò sí ohun tí òfin sọ di pípé. A wá ṣe ètò ìrètí tí ó dára ju òfin lọ nípa èyí tí a lè fi súnmọ́ Ọlọrun. Ìrètí yìí ní ìbúra ninu. Àwọn ọmọ Lefi di alufaa láìsí ìbúra. Ṣugbọn pẹlu ìbúra ni, nígbà tí Ọlọrun sọ fún un pé, “Oluwa ti búra, kò ní yí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pada: ‘Ìwọ máa jẹ́ alufaa títí lae.’ ” Báyìí ni Jesu ṣe di onígbọ̀wọ́ majẹmu tí ó dára ju ti àtijọ́ lọ. Àwọn alufaa ìdílé Lefi pọ̀ nítorí ikú kò jẹ́ kí èyíkéyìí ninu wọn lè wà títí ayé. Ṣugbọn ní ti Jesu, ó wà títí. Nítorí náà kò sí ìdí tí a óo fi tún yan alufaa mìíràn dípò rẹ̀. Ìdí nìyí tí ó fi lè gba àwọn tí wọ́n bá súnmọ́ Ọlọrun nípasẹ̀ rẹ̀ là, lọ́nà gbogbo títí lae nítorí pé ó wà láàyè títí láti máa bẹ̀bẹ̀ fún wọn. Irú olórí alufaa bẹ́ẹ̀ ni ó yẹ wá. Ẹni mímọ́; tí kò ní ẹ̀tàn, tí kò ní àbùkù, tí kò bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kẹ́gbẹ́, tí a gbé ga kọjá àwọn ọ̀run. Òun kì í ṣe ẹni tí ó níláti kọ́kọ́ rúbọ lojoojumọ fún ẹ̀ṣẹ̀ ti ara rẹ̀, kí ó tó wá rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan, bí àwọn olórí alufaa ti ìdílé Lefi ti ń ṣe. Nítorí lẹ́ẹ̀kan náà ni ó ti ṣe èyí, nígbà tí ó fi ara rẹ̀ rúbọ. Nítorí àwọn tí à ń yàn bí olórí alufaa lábẹ́ òfin Mose jẹ́ eniyan, wọ́n sì ní àìlera. Ṣugbọn olórí alufaa tí a yàn nípa ọ̀rọ̀ ìbúra tí ó dé lẹ́yìn òfin ni Ọmọ Ọlọrun tí a ṣe ní àṣepé títí lae. Kókó ohun tí à ń sọ nìyí, pé a ní irú Olórí Alufaa báyìí, ẹni tí ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ ọlá ńlá ní ọ̀run. Òun yìí ni òjíṣẹ́ ní ilé ìsìn tí ó mọ́ jùlọ tíí ṣe àgọ́ tòótọ́, tí Oluwa fúnrarẹ̀ kọ́, kì í ṣe èyí tí eniyan kọ́. Nítorí gbogbo Olórí Alufaa tí a bá yàn, a yàn wọ́n pé kí wọ́n máa mú ẹ̀bùn ati ẹbọ àwọn eniyan wá siwaju Ọlọrun ni. Bákan náà ni òun náà níláti ní àwọn ohun tí yóo máa mú wá siwaju Ọlọrun. Bí ó bá jẹ́ pé ó wà ninu ayé, kì bá tí jẹ́ alufaa rárá, nítorí àwọn alufaa wà tí wọn ń mú ẹ̀bùn àwọn eniyan lọ siwaju Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin. Àwọn yìí ń ṣe ìsìn wọn ninu ilé ìsìn tí ó jẹ́ ẹ̀dà ati àfijọ ti ọ̀run. A rí i pé bẹ́ẹ̀ ni ó rí nítorí nígbà tí Mose fẹ́ kọ́ àgọ́, ohun tí Ọlọrun sọ fún un ni pé, “Ṣe akiyesi pé o ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí àwòrán tí mo fihàn ọ́ ní orí òkè.” Ṣugbọn nisinsinyii iṣẹ́ ìsìn ti Olórí Alufaa wa dára pupọ ju ti àwọn ọmọ Lefi lọ, nítorí pé majẹmu tí ó jẹ́ alárinà fún dára ju ti àtijọ́ lọ, ìdí ni pé ìlérí tí ó dára ju ti àtijọ́ lọ ni majẹmu yìí dúró lé lórí. Bí majẹmu ti àkọ́kọ́ kò bá ní àbùkù, kò sí ìdí tí à bá fi fi òmíràn dípò rẹ̀. Nítorí Ọlọrun rí ẹ̀ṣẹ̀ kà sí wọn lọ́rùn ni ó fi sọ pé, “Oluwa wí pé: Ọjọ́ ń bọ̀ tí èmi yóo bá ilé Israẹli ati ilé Juda dá majẹmu titun. Kì í ṣe irú majẹmu tí mo bá àwọn baba wọn dá ní ọjọ́ tí mo fà wọ́n lọ́wọ́ jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. Nítorí wọn kò pa majẹmu mi mọ́, mo bá kẹ̀yìn sí wọn. Èyí ni majẹmu tí n óo bá ilé Israẹli dá nígbà tí ó bá yá. N óo fi òfin mi sí inú wọn, n óo kọ ọ́ sí ọkàn wọn, èmi óo jẹ́ Ọlọrun wọn, àwọn náà yóo sì jẹ́ eniyan mi. Kì yóo sí ìdí tí ẹnìkan yóo fi kọ́ aládùúgbò rẹ̀ tabi arakunrin rẹ̀, pé, ‘Mọ Oluwa.’ Nítorí pé gbogbo wọn ni wọn óo mọ̀ mí, ohun tí ó ṣẹ̀ láti orí àwọn mẹ̀kúnnù inú wọn títí dé orí àwọn eniyan pataki pataki. Nítorí n óo fi àánú fojú fo ìwà burúkú wọn, n kò sì ní ranti ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.” Nígbà tí ó sọ̀rọ̀ nípa majẹmu titun, ohun tí ó ń sọ ni pé ti àtijọ́ ti di ògbólógbòó. Ohun tí ó bá sì ti di ògbólógbòó, kò níí pẹ́ parẹ́. Majẹmu àkọ́kọ́ ni àwọn ètò ìsìn ati ilé ìsìn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ti ayé ni. Nítorí wọ́n pa àgọ́ àkọ́kàn, ninu rẹ̀ ni ọ̀pá fìtílà ati tabili wà. Lórí tabili yìí ni burẹdi máa ń wà, níwájú Oluwa nígbà gbogbo. Èyí ni à ń pè ní Ibi Mímọ́. Lẹ́yìn aṣọ ìkélé keji ni àgọ́ tí à ń pè ní Ibi Mímọ́ jùlọ wà. Níbẹ̀ ni pẹpẹ wúrà wà fún sísun turari, ati àpótí majẹmu tí a fi wúrà bò yíká. Ninu àpótí yìí ni apẹ wúrà kékeré kan wà tí wọ́n fi mana sí ninu, ati ọ̀pá Aaroni tí ó rúwé nígbà kan rí, ati àwọn wàláà òkúta tí a kọ òfin mẹ́wàá sí. Ní òkè àpótí yìí ni àwọn kerubu ògo Ọlọrun wà, tí òjìji wọn bo ìtẹ́ àánú. N kò lè sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan yìí fínnífínní ní àkókò yìí. Bí a ti ṣe ṣe ètò gbogbo nǹkan wọnyi nìyí. Ninu àgọ́ àkọ́kàn ni àwọn alufaa ti máa ń ṣe wọlé-wọ̀de nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ ìsìn wọn. Ṣugbọn, Olórí Alufaa nìkan ní ó máa ń wọ inú àgọ́ keji. Lẹ́ẹ̀kan lọ́dún sì ni. Òun náà kò sì jẹ́ wọ ibẹ̀ láì mú ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́, tí yóo fi rúbọ fún ara rẹ̀ ati fún ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn eniyan bá ṣèèṣì dá. Ẹ̀mí Mímọ́ fihàn nípa èyí pé ọ̀nà ibi mímọ́ kò ì tíì ṣí níwọ̀n ìgbà tí àgọ́ ekinni bá wà. Àkàwé ni gbogbo èyí jẹ́ fún àkókò yìí. Àwọn ẹ̀bùn ati ẹbọ tí wọn ń rú nígbà náà kò lè fún àwọn tí ó ń rú wọn ní ìbàlẹ̀ àyà patapata. Ohun tí a rí dì mú ninu wọn kò ju nípa jíjẹ ati mímu lọ, ati nípa oríṣìíríṣìí ọ̀nà ìwẹ ọwọ́, wẹ ẹsẹ̀. Ìwọ̀nyí jẹ́ ìlànà àwọn nǹkan tí a lè fojú rí, tí yóo sì máa wà títí di àkókò àtúnṣe. Ṣugbọn Kristi ti dé, òun sì ni Olórí Alufaa àwọn ohun rere tí ó wà. Ó ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ ninu àgọ́ tí ó pé tí ó sì tóbi ju ti àtijọ́ lọ, àgọ́ tí a kò fi ọwọ́ kọ́, tí kì í sì í ṣe ti ẹ̀dá ayé yìí. Kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ tabi ti mààlúù bíkòṣe ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀, ni ó fi rúbọ, nígbà tí ó wọ inú Ibi Mímọ́ jùlọ lọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láti ṣe ìràpadà ayérayé fún wa. Nítorí bí ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ ati ti mààlúù ati eérú abo mààlúù tí a bù wọ́n àwọn tí wọ́n bá ṣe ohun èérí nípa ẹ̀sìn bá sọ wọ́n di mímọ́ lóde ara, mélòó-mélòó ni ẹ̀jẹ̀ Kristi, tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ tí kò lábùkù sí Ọlọrun nípa Ẹ̀mí ayérayé, yóo wẹ ẹ̀rí-ọkàn wa mọ́ kúrò ninu iṣẹ́ tíí yọrí sí ikú, tí yóo sì fi ṣe wá yẹ fún ìsìn Ọlọrun alààyè. Nítorí èyí, òun ni alárinà majẹmu. Ó kú kí ó lè ṣe ìràpadà fún ẹ̀ṣẹ̀ tí eniyan dá lábẹ́ majẹmu àkọ́kọ́, kí àwọn tí Ọlọrun pè lè gba ìlérí ogún ayérayé. Nítorí bí eniyan bá ṣe ìwé bí òun ti fẹ́ kí wọ́n pín ogún òun, ìdánilójú kọ́kọ́ gbọdọ̀ wà pé ó ti kú kí ẹnikẹ́ni tó lè mú ìwé náà lò. Ìwé ìpíngún kò wúlò níwọ̀n ìgbà tí ẹni tí ó ṣe é bá wà láàyè. Ó di ìgbà tí ó bá kú. Ìdí nìyí tí ó fi jẹ́ pé pẹlu ẹ̀jẹ̀ ni a fi ṣe majẹmu àkọ́kọ́. Gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin, nígbà tí Mose bá ti ka gbogbo àṣẹ Ọlọrun fún àwọn eniyan tán, a mú ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ mààlúù ati ti ewúrẹ́ pẹlu omi, ati òwú pupa ati ẹ̀ka igi hisopu, a fi wọ́n Ìwé Òfin náà ati gbogbo àwọn eniyan. A wá sọ pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ majẹmu tí Ọlọrun pa láṣẹ fun yín.” Bákan náà ni yóo fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n ara àgọ́ náà ati gbogbo ohun èèlò ti ìsìn. Gẹ́gẹ́ bí ìlànà ti òfin, ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo nǹkan pátá ni à ń fi ẹ̀jẹ̀ sọ di mímọ́, ati pé láìsí ìtasílẹ̀ ẹ̀jẹ̀ kò lè sí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí náà, nígbà tí ó jẹ́ pé a níláti fi ẹbọ sọ ẹ̀dà àwọn nǹkan ti ọ̀run di mímọ́, a rí i pé àwọn nǹkan ti ọ̀run fúnra wọn nílò ẹbọ tí ó dára ju èyí tí ẹ̀dà wọn gbà lọ. Nítorí kì í ṣe àgọ́ tí a fi ọwọ́ kọ́ ni Kristi wọ̀ lọ, èyí tíí ṣe ẹ̀dà ti àgọ́ tòótọ́. Ṣugbọn ọ̀run gan-an ni ó wọ̀ lọ, nisinsinyii ó wà níwájú Ọlọrun nítorí tiwa. Kì í sìí ṣe pé à-rú-tún-rú ni yóo máa fi ara rẹ̀ rúbọ, bí Olórí Alufaa ti ìdílé Lefi ti máa ń wọ Ibi Mímọ́ jùlọ lọ ní ọdọọdún pẹlu ẹ̀jẹ̀ tí kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, ọpọlọpọ ìgbà ni ìbá ti máa jìyà láti ìgbà tí a ti fi ìdí ayé sọlẹ̀. Ṣugbọn ó fi ara hàn lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo nígbà tí àkókò òpin dé, láti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ nù nípa ẹbọ ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo tí ó fi ara rẹ̀ rú. Dandan ni pé kí gbogbo eniyan kú lẹ́ẹ̀kan, lẹ́yìn ikú ìdájọ́ ló kàn. Bákan náà ni Kristi, nígbà tí a ti fi rúbọ lẹ́ẹ̀kan láti kó ẹ̀ṣẹ̀ ọpọlọpọ lọ, yóo tún pada lẹẹkeji, kì í ṣe láti tún ru ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, ṣugbọn láti gba àwọn tí ó ń fi ìtara retí rẹ̀ là. Nítorí Òfin Mose jẹ́ òjìji àwọn ohun rere tí ń bọ̀, kì í ṣe àwòrán wọn gan-an. Òfin ṣe ìlànà nípa irú ẹbọ kan náà tí àwọn eniyan yóo máa rú lọdọọdun. Ṣugbọn òfin kò lè sọ àwọn tí ń wá siwaju Ọlọrun di pípé. Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ẹbọ yìí ti sọ àwọn tí ń rú wọn di pípé ni, wọn kì bá tí rú wọn mọ́, nítorí ẹ̀rí-ọkàn wọn kì bá tí dá wọn lẹ́bi mọ́ bí ó bá jẹ́ pé ẹbọ tí wọ́n rú lẹ́ẹ̀kan bá ti wẹ̀ wọ́n mọ́. Ṣugbọn àwọn ẹbọ wọnyi ń mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sí ìrántí lọdọọdun, nítorí ẹ̀jẹ̀ mààlúù ati ti ewúrẹ́ kò lè kó ẹ̀ṣẹ̀ lọ. Nítorí náà, nígbà tí Kristi wọ inú ayé wá, ó sọ fún Ọlọrun pé, “Kì í ṣe ẹbọ ati ọrẹ ni o fẹ́, ṣugbọn o ti ṣe ètò ara kan fún mi. Kì í ṣe ẹbọ sísun ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni o ní inú dídùn sí. Nígbà náà ni mo sọ pé, ‘Èmi nìyí. Àkọsílẹ̀ wà ninu Ìwé Mímọ́ nípa mi pé, Ọlọrun, mo dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ.’ ” Ní àkọ́kọ́ ó ní, “Kì í ṣe ẹbọ ati ọrẹ tabi ẹbọ sísun ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni o fẹ́, kì í ṣe àwọn ni inú rẹ dùn sí.” Àwọn ẹbọ tí wọn ń rú nìyí gẹ́gẹ́ bí ìlànà ti Òfin. Lẹ́yìn náà ó wá sọ pé, “Èmi nìyí, mo dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ.” Èyí ni pé ó mú ti àkọ́kọ́ kúrò kí ó lè fi ekeji lélẹ̀. Nípa ìfẹ́ Ọlọrun náà ni a fi yà wá sọ́tọ̀ nítorí ẹbọ tí Jesu fi ara rẹ̀ rú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Àwọn alufaa a máa dúró lojoojumọ láti ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn, láti máa rú ẹbọ kan náà tí kò lè kó ẹ̀ṣẹ̀ lọ nígbàkúùgbà. Ṣugbọn òun ṣe ìrúbọ lẹ́ẹ̀kan fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó tó fún gbogbo ìgbà, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun. Níbẹ̀ ni ó wà tí ó ń retí ìgbà tí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóo di àpótí-ìtìsẹ̀ rẹ̀. Nítorí nípa ẹbọ kan ó sọ àwọn tí a yà sọ́tọ̀ di pípé títí lae. Nítorí Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ náà fún wa. Ó kọ́kọ́ sọ báyìí pé, “Èyí ni majẹmu tí n óo bá wọn dá nígbà tí ó bá yá, Èmi Oluwa ni mo sọ bẹ́ẹ̀, Èmi óo fi òfin mi sí ọkàn wọn, n óo kọ wọ́n sí àyà wọn.” Ó tún ní, “N kò ní ranti ẹ̀ṣẹ̀ ati ìwà burúkú wọn mọ́.” Nígbà tí a bá ti dárí àwọn nǹkan wọnyi ji eniyan, kò tún sí ìrúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. Nítorí náà, ẹ̀yin ará, a ní ìgboyà láti wọ Ibi Mímọ́ jùlọ tí ó wà lẹ́yìn aṣọ ìkélé nípa ẹ̀jẹ̀ Jesu, nípa ọ̀nà titun ati ọ̀nà ààyè tí ó ti yà sọ́tọ̀ fún wa tíí ṣe ẹran-ara rẹ̀. A tún ní alufaa àgbà tí ó wà lórí ìdílé Ọlọrun. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pẹlu òtítọ́ ọkàn ati igbagbọ tí ó kún, kí á fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wẹ ọkàn wa mọ́, kí ó wẹ ẹ̀rí-ọkàn burúkú wa nù, kí á fi omi mímọ́ wẹ ara wa. Kí á di ìjẹ́wọ́ ìrètí wa mú ṣinṣin láì ṣiyèméjì nítorí ẹni tí ó tó ó gbẹ́kẹ̀lé ni ẹni tí ó ṣe ìlérí. Ẹ jẹ́ kí á máa rò nípa bí a óo ti ṣe fún ara wa ní ìwúrí láti ní ìfẹ́ ati láti ṣe iṣẹ́ rere. Ẹ má jẹ́ kí á máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, bí àṣà àwọn mìíràn, ṣugbọn kí á máa gba ara wa níyànjú, pataki jùlọ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ti rí i pé ọjọ́ ńlá ọ̀hún súnmọ́ tòsí. Nítorí bí a bá mọ̀ọ́nmọ̀ dẹ́ṣẹ̀ lẹ́yìn tí a ti ní ìmọ̀ òtítọ́, kò tún sí ẹbọ kan tí a lè rú fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. Ohun tí ó kù ni pé kí á máa retí ìdájọ́ pẹlu ìpayà ati iná ńlá tí yóo pa àwọn ọ̀tá Ọlọrun. Bí ẹni meji tabi mẹta bá jẹ́rìí pé ẹnìkan ṣá Òfin Mose tì, pípa ni wọn yóo pa olúwarẹ̀ láì ṣàánú rẹ̀. Irú ìyà ńlá wo ni ẹ rò pé Ọlọrun yóo fi jẹ ẹni tí ó kẹ́gàn Ọmọ rẹ̀, tí ó rò pé nǹkan lásán ni ẹ̀jẹ̀ majẹmu tí a fi yà á sọ́tọ̀, tí ó sì ṣe àfojúdi sí Ẹ̀mí tí a fi gba oore-ọ̀fẹ́? Nítorí a mọ ẹni tí ó sọ pé, “Tèmi ni ẹ̀san, Èmi yóo sì gbẹ̀san.” Ati pé, “Oluwa ni yóo ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan rẹ̀.” Ohun tí ó bani lẹ́rù gidigidi ni pé kí ọwọ́ Ọlọrun alààyè tẹ eniyan. Ẹ ranti bí a ti ja ìjà líle, tí ẹ farada ìrora, látijọ́, nígbà tí ẹ kọ́kọ́ rí ìmọ́lẹ̀ igbagbọ. Nígbà mìíràn wọ́n fi yín ṣẹ̀sín, wọ́n jẹ yín níyà, àwọn eniyan ń fi yín ṣe ìran wò. Nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀, ẹ dúró láì yẹsẹ̀ pẹlu àwọn tí wọ́n ti jẹ irú ìyà bẹ́ẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ bá àwọn ẹlẹ́wọ̀n jìyà. Pẹlu ayọ̀ ni ẹ fi gbà kí wọ́n fi agbára kó àwọn dúkìá yín lọ, nítorí ẹ mọ̀ pé ẹ ní dúkìá tí ó tún dára ju èyí tí wọn kó lọ, tí yóo sì pẹ́ jù wọ́n lọ. Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀mí ìfọkàntán tí ẹ ní bọ́, nítorí ó ní èrè pupọ. Ohun tí ẹ nílò ni ìfaradà, kí ẹ lè ṣe ìfẹ́ Ọlọrun, kí ẹ baà lè gba ìlérí tí ó ṣe. Nítorí náà, bí Ìwé Mímọ́ ti wí, “Nítorí láìpẹ́ jọjọ, ẹni tí ń bọ̀ yóo dé, kò ní pẹ́ rárá. Ṣugbọn àwọn olódodo tí wọ́n jẹ́ tèmi yóo wà láàyè nípa igbagbọ. Ṣugbọn bí èyíkéyìí ninu wọn bá fà sẹ́yìn inú mi kò ní dùn sí i.” Ṣugbọn àwa kò sí ninu àwọn tí wọn ń fà sẹ́yìn sí ìparun. Ṣugbọn àwa ní igbagbọ, a sì ti rí ìgbàlà. Igbagbọ ni ìdánilójú ohun tí à ń retí, ẹ̀rí tí ó dájú nípa àwọn ohun tí a kò rí. Igbagbọ ni àwọn àgbà àtijọ́ ní, tí wọ́n fi ní ẹ̀rí rere. Nípa igbagbọ ni ó fi yé wa pé ọ̀rọ̀ ni Ọlọrun fi dá ayé, tí ó fi jẹ́ pé ohun tí a kò rí ni ó fi ṣẹ̀dá ohun tí a rí. Nípa igbagbọ ni Abeli fi rú ẹbọ tí ó dára ju ti Kaini lọ sí Ọlọrun. Igbagbọ rẹ̀ ni ẹ̀rí pé a dá a láre, nígbà tí Ọlọrun gba ọrẹ rẹ̀. Nípa igbagbọ ni ó fi jẹ́ pé bí ó tilẹ̀ ti kú, sibẹ ó ń sọ̀rọ̀. Nípa igbagbọ ni a fi mú Enọku kúrò ní ayé láìjẹ́ pé ó kú. Ẹnikẹ́ni kò rí i mọ́ nítorí pé Ọlọrun ti mú un lọ. Nítorí kí ó tó mú un lọ, Ìwé Mímọ́ sọ nípa rẹ̀ pé, “Ó ṣe ohun tí ó wu Ọlọrun.” Láìsí igbagbọ eniyan kò lè ṣe ohun tí ó wu Ọlọrun. Nítorí ẹni tí ó bá wá sọ́dọ̀ Ọlọrun níláti gbàgbọ́ pé Ọlọrun wà, ati pé òun ni ó ń fún àwọn tí ó bá ń wá a ní èrè. Nípa igbagbọ ni Noa fi kan ọkọ̀ kan, nígbà tí Ọlọrun ti fi àṣírí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ hàn án. Ó fi ọ̀wọ̀ gba iṣẹ́ tí Ọlọrun rán sí i, ó sì kan ọkọ̀ fún ìgbàlà ìdílé rẹ̀. Nípa igbagbọ ó fi ìṣìnà aráyé hàn, ó sì ti ipa rẹ̀ di ajogún òdodo. Nípa igbagbọ ni Abrahamu fi gbà nígbà tí Ọlọrun pè é pé kí ó jáde lọ sí ilẹ̀ tí òun óo fún un. Ó jáde lọ láìmọ̀ ibi tí ó ń lọ. Nípa igbagbọ ni ó fi ń gbé ilẹ̀ ìlérí bí àlejò, ó ń gbé inú àgọ́ bíi Isaaki ati Jakọbu, àwọn tí wọn óo jọ jogún ìlérí kan náà. Nítorí ó ń retí ìlú tí ó ní ìpìlẹ̀, tí ó jẹ́ pé Ọlọrun ni ó ṣe ètò rẹ̀ tí ó sì kọ́ ọ. Nípa igbagbọ, Abrahamu ní agbára láti bímọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Sara yàgàn, ó sì ti dàgbà kọjá ọmọ bíbí, Abrahamu gbà pé ẹni tí ó ṣèlérí tó gbẹ́kẹ̀lé. Nítorí èyí, láti ọ̀dọ̀ ẹyọ ọkunrin kan, tí ó ti dàgbà títí, tí ó ti kú sára, ni ọpọlọpọ ọmọ ti jáde, wọ́n pọ̀ bíi ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ati bíi iyanrìn etí òkun. Gbogbo àwọn wọnyi kú ninu igbagbọ. Wọn kò rí ohun tí Ọlọrun ṣe ìlérí gbà, òkèèrè ni wọ́n ti rí i, wọ́n sì ń fi ayọ̀ retí rẹ̀. Wọ́n jẹ́wọ́ pé àlejò tí ń rékọjá lọ ni àwọn ní ayé. Àwọn eniyan tí ó bá ń sọ̀rọ̀ báyìí fihàn pé wọ́n ń wá ìlú ti ara wọn. Bí ó bá jẹ́ pé wọ́n tún ń ronú ti ibi tí wọ́n ti jáde wá, wọn ìbá ti wá ààyè láti pada sibẹ. Ṣugbọn wọ́n ń dàníyàn fún ìlú tí ó dára ju èyí tí wọ́n ti jáde kúrò lọ, tíí ṣe ìlú ti ọ̀run. Nítorí náà Ọlọrun kò tijú pé kí á pe òun ní Ọlọrun wọn, nítorí ó ti ṣe ètò ìlú kan fún wọn. Nípa igbagbọ ni Abrahamu fi Isaaki rúbọ nígbà tí Ọlọrun dán an wò. Ó fi ààyò ọmọ rẹ̀ rúbọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọrun ti ṣe ìlérí fún un nípa rẹ̀, tí Ọlọrun ti sọ fún un pé, “Láti inú Isaaki ni ìdílé rẹ yóo ti gbilẹ̀.” Èrò rẹ̀ ni pé Ọlọrun lè tún jí eniyan dìde ninu òkú. Nítorí èyí, àfi bí ẹni pé ó tún gba ọmọ náà pada láti inú òkú. Nípa igbagbọ ni Isaaki fi súre fún Jakọbu ati Esau tí ó sì sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí wọn. Nígbà tí Jakọbu ń kú lọ, nípa igbagbọ ni ó fi súre fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Josẹfu. Ó ń sin Ọlọrun bí ó ti tẹríba lórí ọ̀pá rẹ̀. Nígbà tí ó tó àkókò tí Josẹfu yóo kú, nípa igbagbọ ni ó fi ranti pé àwọn ọmọ Israẹli yóo jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, tí ó sì sọ bí òun ti fẹ́ kí wọ́n ṣe egungun òun. Nígbà tí wọ́n bí Mose, nípa igbagbọ ni àwọn òbí rẹ̀ fi gbé e pamọ́ fún oṣù mẹta nítorí wọ́n rí i pé ọmọ tí ó lẹ́wà ni, wọn kò sì bẹ̀rù àṣẹ ọba. Nígbà tí Mose dàgbà tán, nípa igbagbọ ni ó fi kọ̀, tí kò jẹ́ kí wọ́n pe òun ní ọmọ ọmọbinrin Farao. Ó kúkú yàn láti jìyà pẹlu àwọn eniyan Ọlọrun jù pé kí ó jẹ ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ lọ. Ó ka ẹ̀gàn nítorí Mesaya sí ọrọ̀ tí ó tóbi ju gbogbo ìṣúra Ijipti lọ, nítorí ó ń wo èrè níwájú. Nípa igbagbọ ni ó fi kúrò ní Ijipti, kò bẹ̀rù ibinu ọba, ó ṣe bí ẹni tí ó rí Ọlọrun tí a kò lè rí, kò sì yẹ̀ kúrò ní ọ̀nà tí ó ti yàn. Nípa igbagbọ ni ó fi ṣe Àjọ̀dún Ìrékọjá ati ètò láti fi ẹ̀jẹ̀ ra ara ìlẹ̀kùn, kí angẹli tí ń pa àwọn àkọ́bí ọmọ àwọn ará Ijipti má baà fọwọ́ kan ọmọ àwọn eniyan Israẹli. Nípa igbagbọ ni àwọn ọmọ Israẹli fi gba ààrin òkun pupa kọjá bí ìgbà tí eniyan ń rìn lórí ilẹ̀ gbígbẹ. Nígbà tí àwọn ará Ijipti náà gbìyànjú láti kọjá, rírì ni wọ́n rì sinu omi. Nípa igbagbọ ni odi ìlú Jẹriko fi wó lulẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Israẹli ti yí i ká fún ọjọ́ meje. Nípa igbagbọ ni Rahabu aṣẹ́wó kò fi kú pẹlu àwọn alaigbagbọ, nígbà tí ó ti fi ọ̀yàyà gba àwọn amí. Kí ni kí n tún wí? Àyè kò sí fún mi láti sọ nípa Gideoni, Baraki, Samsoni, Jẹfuta, Dafidi, Samuẹli ati àwọn wolii. Nípa igbagbọ, wọ́n ṣẹgun ilẹ̀ àwọn ọba, wọn ṣiṣẹ́ tí òdodo fi gbilẹ̀, wọ́n rí ìlérí Ọlọrun gbà. Wọ́n pa kinniun lẹ́nu mọ́. Wọ́n pa iná ńlá. Wọ́n bọ́ lọ́wọ́ idà. A sọ wọ́n di alágbára nígbà tí wọn kò ní ìlera. Wọ́n di akọni lójú ogun. Wọ́n tú àwọn ọmọ-ogun ilẹ̀ àjèjì ká tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi sá pada sẹ́yìn. Àwọn obinrin gba àwọn eniyan wọn tí wọ́n ti kú pada lẹ́yìn tí a ti jí wọn dìde kúrò ninu òkú. A dá àwọn mìíràn lóró títí wọ́n fi kú. Wọn kò pé kí á dá wọn sílẹ̀, nítorí kí wọ́n lè gba ajinde tí ó dára jùlọ. A fi àwọn mìíràn ṣẹ̀sín. Wọ́n fi kòbókò na àwọn mìíràn. A fi ẹ̀wọ̀n de àwọn mìíràn. A sọ àwọn mìíràn sẹ́wọ̀n. A sọ àwọn mìíràn lókùúta. A fi ayùn rẹ́ àwọn mìíràn sí meji. A fi idà pa àwọn mìíràn. Àwọn mìíràn ń rìn kiri, wọ́n wọ awọ aguntan ati awọ ewúrẹ́, ninu ìṣẹ́ ati ìpọ́njú ati ìnira. Wọ́n dára ju kí wọ́n wà ninu ayé lọ. Wọ́n ń dá rìn kiri ninu aṣálẹ̀, níbi tí eniyan kì í gbé, lórí òkè, ninu ihò inú òkúta ati ihò inú ilẹ̀. Gbogbo àwọn wọnyi ni ẹ̀rí rere nípa igbagbọ, ṣugbọn wọn kò rí ohun tí Ọlọrun ti ṣe ìlérí gbà. Nítorí pé àwa ni Ọlọrun ní lọ́kàn tí ó fi ṣe ètò tí ó dára jùlọ, pé kí àwa ati àwọn lè jọ rí ẹ̀kún ibukun gbà. Níwọ̀n ìgbà tí a ní àwọn tí wọn ń jẹ́rìí sí agbára igbagbọ, tí wọ́n yí wa ká bí awọsanma báyìí, ẹ jẹ́ kí á pa gbogbo ohun ìdíwọ́ tì sápá kan, ati àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó rọrùn láti jẹ́ kí wọ́n dì mọ́ wa. Kí á fi ìfaradà sá iré ìje tí ó wà níwájú wa. Kí á máa wo Jesu olùpilẹ̀ṣẹ̀ ati aláṣepé igbagbọ wa. Ẹni tí ó farada agbelebu, kò sì ka ìtìjú ikú lórí agbelebu sí nǹkankan nítorí ayọ̀ tí ó wà níwájú rẹ̀. Ó ti wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọrun. Ẹ ro ti irú ẹni bẹ́ẹ̀ tí ó fọkàn rán àtakò àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, kí ọkàn yín má baà rẹ̀wẹ̀sì. Ninu ìjàkadì yín ẹ kò ì tíì tako ẹ̀ṣẹ̀ dé ojú ikú. Ẹ ti gbàgbé ọ̀rọ̀ ìyànjú inú Ìwé Mímọ́ níbi tí ó ti pè yín ní ọmọ, nígbà tí ó sọ pé, Ọmọ mi, má ṣe ka ìtọ́sọ́nà Oluwa sí nǹkan yẹpẹrẹ má sì jẹ́ kí ọkàn rẹ rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí ó bá ń bá ọ wí. Nítorí ẹni tí Oluwa bá fẹ́ràn ni ó ń tọ́ sọ́nà, ẹni tí ó bá gbà bí ọmọ, ni ó ń nà ní pàṣán. Ẹ níláti faradà á bí ìtọ́sọ́nà. Ọlọrun mú yín bí ọmọ ni. Nítorí ọmọ wo ni ó wà tí baba rẹ̀ kò ní tọ́ sọ́nà? Bí ẹ kò bá ní irú ìtọ́sọ́nà tí gbogbo ọmọ máa ń ní, á jẹ́ pé ọmọ àlè ni yín, ẹ kì í ṣe ọmọ tòótọ́. Ṣebí a ní àwọn baba tí wọ́n bí wa, tí wọn ń tọ́ wa sọ́nà, tí a sì ń bu ọlá fún wọn. Báwo ni ó wá yẹ kí á bọ̀wọ̀ fún Baba wa nípa ti ẹ̀mí tó, kí á sì ní ìyè? Fún ìgbà díẹ̀ ni àwọn baba wa nípa ti ara fi ń tọ́ wa, bí ó bá ti dára lójú wọn. Ṣugbọn Baba wa nípa ti ẹ̀mí ń tọ́ wa fún ire wa, kí á lè bá a pín ninu ìwà mímọ́ rẹ̀. Ní àkókò tí a bá ń sọ fún eniyan pé: má ṣe èyí, má ṣe tọ̀hún, kì í dùn mọ́ ẹni tí à ń tọ́. Pẹlu ìnira ni. Ṣugbọn ní ìgbẹ̀yìn a máa so èso alaafia ti ìgbé-ayé òdodo fún àwọn tí a bá ti tọ́ sọ́nà. Nítorí náà ẹ gbé ọwọ́ yín tí kò lágbára sókè, ẹ mú kí eékún yín tí ń gbọ̀n di alágbára; ẹ ṣe ọ̀nà títọ́ fún ara yín láti máa rìn, kí ẹsẹ̀ tí ó bá ti rọ má baà yẹ̀, ṣugbọn kí ó lè mókun. Ẹ máa lépa alaafia lọ́dọ̀ gbogbo eniyan pẹlu ìwà mímọ́. Láìṣe bẹ́ẹ̀ kò sí ẹni tí yóo rí Oluwa. Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni ninu yín má fà sẹ́yìn kúrò ninu oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun. Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má ṣe dàbí igi kíkorò, tí yóo dàgbà tán tí yóo wá fi ìkorò tirẹ̀ kó ìdààmú bá ọpọlọpọ ninu yín. Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má jẹ́ oníṣekúṣe tabi alaigbagbọ bíi Esau, tí ó tìtorí oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan péré ta anfaani tí ó ní gẹ́gẹ́ bí àrólé baba rẹ̀. Ẹ mọ̀ pé nígbẹ̀yìn, nígbà tí ó fẹ́ gba ìre tí ó tọ́ sí àrólé, baba rẹ̀ ta á nù. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fi omijé wá ọ̀nà àtúnṣe, kò sí ààyè mọ́ fún ìrònúpìwàdà. Nítorí kì í ṣe òkè Sinai ni ẹ wá, níbi tí iná ti ń jó, tí ó ṣú dẹ̀dẹ̀ tí ó ṣókùnkùn tí afẹ́fẹ́ líle sì ń fẹ́, tí fèrè ń dún kíkankíkan, tí ohùn kan wá ń sọ̀rọ̀ ní ọ̀nà tí ó jẹ́ pé àwọn tí ń gbọ́ ọ bẹ̀bẹ̀, pé kí àwọn má tún gbọ́ irú rẹ̀ mọ́. Nítorí ìjayà bá wọn nígbà tí a pàṣẹ fún wọn pé, “Bí ẹranko bá fi ara kan òkè náà, a níláti sọ ọ́ ní òkúta pa ni!” Ohun tí wọ́n rí bani lẹ́rù tóbẹ́ẹ̀ tí Mose fi sọ pé, “Ẹ̀rù ń bà mí! Gbígbọ̀n ni gbogbo ara mi ń gbọ̀n látòkè délẹ̀.” Ṣugbọn òkè Sioni ni ẹ wá, ìlú Ọlọrun alààyè, Jerusalẹmu ti ọ̀run, pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀nà ẹgbẹrun angẹli. Ẹ wá sí àjọyọ̀ ogunlọ́gọ̀ eniyan, ati ìjọ àwọn àkọ́bí tí a kọ orúkọ wọn sọ́run. Ẹ wá sọ́dọ̀ Ọlọrun onídàájọ́ gbogbo eniyan ati ọ̀dọ̀ ẹ̀mí àwọn ẹni rere tí a ti sọ di pípé, ati ọ̀dọ̀ Jesu, alárinà majẹmu titun, ati sí ibi ẹ̀jẹ̀ tí a fi wọ́n ohun èèlò ìrúbọ tí ó ní ìlérí tí ó dára ju ti Abeli lọ. Ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣàì bìkítà fún ẹni tí ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, nítorí pé nígbà tí àwọn tí wọ́n ṣàì bìkítà fún Ọlọrun nígbà tí ó rán Mose ní iṣẹ́ sí ayé kò bọ́ lọ́wọ́ ìyà, báwo ni àwa ṣe le bọ́ bí a bá ṣàì bìkítà fún ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ láti ọ̀run. Ní àkókò náà ohùn rẹ̀ mi ilẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, ó ti ṣèlérí pé, “Lẹ́ẹ̀kan sí i kì í ṣe ilẹ̀ nìkan ni n óo mì, ṣugbọn n óo mi ilẹ̀, n óo sì mi ọ̀run.” Nígbà tí ó sọ pé, “Lẹ́ẹ̀kan sí i,” ó dájú pé nígbà tí ó mi àwọn nǹkan tí a dá wọnyi, ó ṣetán láti mú wọn kúrò patapata, kí ó lè ku àwọn ohun tí a kò mì. Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti gba ìjọba tí kò ṣe é mì, ẹ jẹ́ kí á dúpẹ́. Ẹ jẹ́ kí á sin Ọlọrun bí ó ti yẹ pẹlu ọ̀wọ̀ ati ẹ̀rù; nítorí iná ajónirun ni Ọlọrun wa. Àwọn onigbagbọ níláti fẹ́ràn ara wọn. Ẹ má gbàgbé láti máa ṣe àlejò nítorí nípa àlejò ṣíṣe àwọn ẹlòmíràn ti ṣe àwọn angẹli lálejò láìmọ̀ pé angẹli ni wọ́n. Ẹ ranti àwọn tí wọ́n wà lẹ́wọ̀n, kí ẹ ṣe bí ẹni pé ẹ̀yin náà wà lẹ́wọ̀n pẹlu wọn. Ẹ tún ranti àwọn tí à ń ni lára pẹlu, nítorí pé inú ayé ni ẹ wà sibẹ, irú nǹkan wọnyi lè ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀yin náà. Ohun tí ó lọ́lá ni igbeyawo. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì yẹ kí gbogbo yín kà á sí. Ibùsùn tọkọtaya gbọdọ̀ jẹ́ aláìléèérí. Nítorí Ọlọrun yóo dájọ́ fún àwọn oníṣekúṣe ati àwọn àgbèrè. Ẹ má jẹ́ kí ìfẹ́ owó gbà yín lọ́kàn. Ẹ ní ìtẹ́lọ́rùn pẹlu ohun tí ẹ ní. Nítorí Ọlọrun fúnrarẹ̀ ti sọ pé, “N kò ní fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní kọ̀ ọ́!” Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, a lè fi ìgboyà sọ pé, “Oluwa ni olùrànlọ́wọ́ mi, ẹ̀rù kò ní bà mí. Ohun yòówù tí eniyan lè ṣe sí mi.” Ẹ ranti àwọn aṣiwaju yín, àwọn tí wọ́n mú ọ̀rọ̀ Ọlọrun wá fun yín. Ẹ ronú nípa iṣẹ́ wọn ati bí wọ́n ṣe kú. Kí ẹ ṣe àfarawé igbagbọ wọn. Bákan náà ni Jesu Kristi wà lánàá, lónìí ati títí lae. Ẹ má ṣe jẹ́ kí oríṣìíríṣìí ẹ̀kọ́ àjèjì mu yín ṣìnà. Ohun tí ó dára ni pé kí ọkàn yín gba agbára nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun, kì í ṣe nípa ìlànà ohun tí a jẹ, tabi ohun tí a kò jẹ, irú ìlànà bẹ́ẹ̀ kò ṣe àwọn tí ó ń tẹ̀lé e ní anfaani. A ní pẹpẹ ìrúbọ kan tí àwọn alufaa tí wọn ń sìn ninu àgọ́ ti ayé kò ní àṣẹ láti jẹ ninu ẹbọ rẹ̀. Nítorí nígbà tí Olórí Alufaa bá wọ Ibi Mímọ́ lọ, wọ́n ń fi ẹ̀jẹ̀ ẹranko rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀. Ṣugbọn sísun ni wọ́n ń sun ẹran ẹbọ wọnyi lẹ́yìn ibùdó. Bákan náà ni Jesu, ó jìyà lẹ́yìn odi ìlú kí ó lè sọ àwọn eniyan di mímọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ òun tìkararẹ̀. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á tọ̀ ọ́ lọ lẹ́yìn ibùdó, kí á gba irú ẹ̀gàn tí ó gbà. Nítorí a kò ní ìlú tí yóo wà títí níhìn-ín, ṣugbọn à ń retí èyí tí ó ń bọ̀! Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á máa rú ẹbọ ìsìn sí Ọlọrun nígbà gbogbo nípasẹ̀ Jesu. Èyí ni ohun tí ó yẹ gbogbo ẹni tí ó bá ń jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀. Ẹ má gbàgbé láti máa ṣe rere, kí ẹ sì máa fún àwọn ẹlòmíràn ninu àwọn ohun ìní yín. Irú ẹbọ yìí ni inú Ọlọrun dùn sí. Kí ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn aṣiwaju yín lẹ́nu, kí ẹ máa tẹ̀lé ìlànà wọn. Nítorí wọ́n ń ṣe akitiyan láìṣe àárẹ̀ láti tọ́jú yín, pẹlu ọkàn pé wọn yóo jíyìn iṣẹ́ wọn fún Ọlọrun. Ẹ mú kí iṣẹ́ wọn jẹ́ ayọ̀ fún wọn, ẹ má jẹ́ kí ó jẹ́ ìrora. Bí ẹ bá mú kí iṣẹ́ wọn jẹ́ ìrora fún wọn, kò ní ṣe yín ní anfaani. Ẹ máa gbadura fún wa. Ó dá wa lójú pé ọkàn wa mọ́. Ohun tí ó dára ni a fẹ́ máa ṣe nígbà gbogbo. Nítorí náà mo tún bẹ̀ yín gidigidi pé kí ẹ máa gbadura fún wa, kí wọ́n baà lè dá mi sílẹ̀ kíákíá láti wá sọ́dọ̀ yín. Kí Ọlọrun alaafia, ẹni tí ó jí Jesu Oluwa wa dìde ninu òkú, Jesu, Olú olùṣọ́-aguntan, ẹni tí ó kú, kí ó baà lè fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣe èdìdì majẹmu ayérayé, kí ó mu yín pé ninu gbogbo ohun rere kí ẹ lè ṣe ìfẹ́ rẹ̀, kí ó lè máa ṣe ohun tí ó wù ú ninu yín nípasẹ̀ Jesu Kristi ẹni tí ògo wà fún lae ati laelae. Amin. *** Mo bẹ̀ yín, ará, kí ẹ gba ọ̀rọ̀ ìyànjú wa yìí nítorí ìwé kúkúrú ni mo kọ si yín. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé wọ́n ti dá Timoti, arakunrin wa, sílẹ̀: ó ti jáde lẹ́wọ̀n. Bí ó bá tètè dé, èmi ati òun ni a óo jọ ri yín. Ẹ kí gbogbo àwọn aṣiwaju yín ati gbogbo àwọn onigbagbọ. Àwọn ará láti Itali ki yín. Kí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun wà pẹlu gbogbo yín. Èmi Jakọbu, iranṣẹ Ọlọrun, ati ti Oluwa wa, Jesu Kristi, ni ó ń kọ ìwé yìí sí àwọn ẹ̀yà mejila tí ó fọ́nká gbogbo ayé. Alaafia fun yín! Ẹ̀yin ará mi, ẹ kà á sí ayọ̀ gidi nígbà tí oríṣìíríṣìí ìdánwò bá dé ba yín. Kí ẹ mọ̀ pé ìdánwò igbagbọ yín ń mú kí ẹ ní ìfaradà. Ẹ níláti ní ìfaradà títí dé òpin, kí ẹ lè di pípé, kí ẹ sì ní ohun gbogbo lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, láìsí ìkùnà kankan. Bí ẹnikẹ́ni bá wà ninu yín, tí ọgbọ́n kù díẹ̀ kí ó tó fún, kí olúwarẹ̀ bèèrè lọ́dọ̀ Ọlọrun, yóo sì fún un. Nítorí Ọlọrun lawọ́, kì í sìí sìrègún. Ṣugbọn olúwarẹ̀ níláti bèèrè pẹlu igbagbọ, láì ṣiyèméjì. Nítorí ẹni tí ó bá ń ṣiyèméjì dàbí ìgbì omi òkun, tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kiri tí ó sì ń rú sókè. Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ má ṣe rò pé òun óo rí nǹkankan gbà lọ́dọ̀ Oluwa: ọkàn rẹ̀ kò papọ̀ sí ọ̀nà kan, ó ń ṣe ségesège, ó ń ṣe iyè meji. *** Kí arakunrin tí ó jẹ́ mẹ̀kúnnù kí ó yọ̀ nígbà tí Ọlọrun bá gbé e ga. Bẹ́ẹ̀ ni kí ọlọ́rọ̀ kí ó yọ̀ nígbà tí Ọlọrun bá rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀, nítorí bí òdòdó koríko ìgbẹ́ ni ọlọ́rọ̀ kò ní sí mọ́. Nítorí nígbà tí oòrùn bá yọ, tí ó mú, koríko á rọ, òdòdó rẹ̀ á sì rẹ̀, òdòdó tí ó lẹ́wà tẹ́lẹ̀ á wá ṣègbé. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ọlọ́rọ̀ yóo parẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Ẹni tí ó bá fi ara da ìdánwò kú oríire, nítorí nígbà tí ó bá yege tán, yóo gba adé ìyè tí Ọlọrun ṣe ìlérí fún àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ̀. Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìdánwò má ṣe sọ pé, “Láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni ìdánwò yìí ti wá.” Nítorí kò sí ẹni tí ó lè fi nǹkan burúkú dán Ọlọrun wò. Ọlọrun náà kò sì jẹ́ fi nǹkan burúkú dán ẹnikẹ́ni wò. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn olukuluku ni ó ń tàn án, tí ó ń fa ìdánwò. Nígbà tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ bá lóyún, á bí ẹ̀ṣẹ̀; nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ bá gbilẹ̀ tán á bí ikú. Ẹ̀yin ará mi olùfẹ́, ẹ má tan ara yín jẹ. Láti òkè ni gbogbo ẹ̀bùn rere ati gbogbo ẹ̀bùn pípé ti ń wá, a máa wá láti ọ̀dọ̀ Baba tí ó dá ìmọ́lẹ̀, baba tí kì í yí pada, tí irú òjìji tíí máa wà ninu ìṣípò pada kò sì sí ninu rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, ó fi ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí wa, kí á lè jẹ́ àkọ́kọ́ ninu àwọn ẹ̀dá rẹ̀. Ẹ̀yin ará mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n, mo fẹ́ kí ẹ mọ nǹkankan: eniyan níláti tètè gbọ́ ọ̀rọ̀, ṣugbọn kí ó lọ́ra láti désì pada, kí ó sì lọ́ra láti bínú. Nítorí ibinu eniyan kì í yọrí sí ire tí Ọlọrun fẹ́. Nítorí náà, ẹ mú gbogbo ìwà èérí ati gbogbo ìwàkiwà à-ń-wá-ipò-aṣaaju kúrò, kí á lè wà ní ipò kinni. Ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ gba ọ̀rọ̀ tí a gbìn sinu yín, tí ó lè gba ọkàn yín là. Ẹ máa fi ọ̀rọ̀ ìyìn rere ṣe ìwà hù; ẹ má kàn máa gbọ́ ọ lásán. Bí ẹ bá ń gbọ́ lásán, ara yín ni ẹ̀ ń tàn jẹ. Nítorí bí eniyan bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí kò fi ṣe ìwà hù, olúwarẹ̀ dàbí ẹni tí ó wo ojú ara rẹ̀ ninu dígí. Ó wo ara rẹ̀ dáradára, ó kúrò níbẹ̀, kíá ó ti gbàgbé bí ojú rẹ̀ ti rí. Ṣugbọn ẹni tí ó bá wo òfin tí ó pé, tíí ṣe orísun òmìnira, tí ó sì dúró lé e lórí, olúwarẹ̀ kì í ṣe ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó gbàgbé rẹ̀, ṣugbọn ó ń fi ọ̀rọ̀ náà ṣe ìwà hù. Olúwarẹ̀ di ẹni ibukun nítorí ó ń fi ọ̀rọ̀ tí ó gbọ́ ṣe ìwà hù. Bí ẹnìkan bá rò pé òun jẹ́ olùfọkànsìn, tí kò bá kó ahọ́n rẹ̀ níjàánu, ó ń tan ara rẹ̀ jẹ ni, asán sì ni ẹ̀sìn rẹ̀. Ẹ̀sìn tí ó pé, tí kò lábàwọ́n níwájú Ọlọrun Baba ni pé kí eniyan máa ran àwọn ọmọ tí kò ní òbí ati àwọn opó lọ́wọ́ ninu ipò ìbànújẹ́ wọn, kí eniyan sì pa ara rẹ̀ mọ́ láìléèérí ninu ayé. Ẹ̀yin ará mi, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ní igbagbọ ninu Oluwa wa, Jesu Kristi, Oluwa tí ó lógo, ẹ má máa ṣe ojuṣaaju. Bí àpẹẹrẹ, bí ẹnìkan bá wọ àwùjọ yín, tí ó fi òrùka wúrà sọ́wọ́, tí ó wọ aṣọ tí ń dán, tí talaka kan náà bá wọlé tí ó wọ aṣọ tí ó dọ̀tí; ẹ óo máa fi ojurere wo ẹni tí ó wọ aṣọ dídán, ẹ óo sọ fún un pé, “Wá jókòó níbi dáradára yìí.” Ṣugbọn ẹ óo wá sọ fún talaka pé, “Dúró níbẹ̀, tabi wá jókòó nílẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ mi níhìn-ín.” Ǹjẹ́ ẹ kò fi bẹ́ẹ̀ dá ìyapa sílẹ̀ láàrin ara yín, ǹjẹ́ ẹ kò sì máa ṣe ìdájọ́ pẹlu èrò burúkú. Ẹ fi etí sílẹ̀, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́. Ọlọrun ti yan àwọn mẹ̀kúnnù ayé yìí láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ ninu igbagbọ ati láti jogún ìjọba tí ó ti ṣe ìlérí fún àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ̀. Ṣugbọn ẹ̀ ń kẹ́gàn mẹ̀kúnnù. Ṣebí àwọn ọlọ́rọ̀ níí máa fìtínà yín, tí wọn máa ń fà yín lọ sí kóòtù! Ṣebí àwọn ni wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí orúkọ rere tí a fi ń pè yín! Ẹ̀ ń ṣe dáradára tí ẹ bá pa òfin ìjọba Ọlọrun mọ́, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti sọ pé, “Ìwọ fẹ́ràn ọmọnikeji rẹ bí o ti fẹ́ràn ara rẹ.” Ṣugbọn tí ẹ bá ń ṣe ojuṣaaju, ẹ di arúfin, ati ẹni ìbáwí lábẹ́ òfin gẹ́gẹ́ bí arúfin. Nítorí ẹni tí ó bá pa gbogbo òfin mọ́, ṣugbọn tí ó rú ẹyọ kan ṣoṣo, ó jẹ̀bi gbogbo òfin. Nítorí ẹnìkan náà tí ó wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè,” òun náà ni ó wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ paniyan.” Bí o kò bá ṣe àgbèrè ṣugbọn o paniyan, o ti di arúfin. Ẹ máa sọ̀rọ̀, kí ẹ sì máa hùwà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó wà lábẹ́ ìdájọ́ òfin tí ó ń sọ eniyan di òmìnira. Nítorí kò ní sí àánú ninu ìdájọ́ fún àwọn tí kò ní ojú àánú, bẹ́ẹ̀ sì ni àánú ló borí ìdájọ́. Ẹ̀yin ará mi, èrè kí ni ó jẹ́, tí ẹnìkan bá sọ pé òun ní igbagbọ, ṣugbọn tí igbagbọ yìí kò hàn ninu iṣẹ́ rẹ̀? Ṣé igbagbọ yìí lè gbà á là? Bí arakunrin kan tabi arabinrin kan bá wà ní ìhòòhò, tí kò jẹun fún odidi ọjọ́ kan, tí ẹnìkan ninu yín wá sọ fún un pé, “Máa lọ ní alaafia, Ọlọrun yóo pèsè aṣọ ati oúnjẹ fún ọ,” ṣugbọn tí kò fún olúwarẹ̀ ní ohun tí ó nílò, anfaani wo ni ọ̀rọ̀ tí ó sọ ṣe? Bẹ́ẹ̀ gan-an ni igbagbọ tí kò bá ní iṣẹ́: òkú ni. Ṣugbọn ẹnìkan lè sọ pé, “Ìwọ ní igbagbọ, èmi ní iṣẹ́.” Fi igbagbọ rẹ hàn mí láìsí iṣẹ́, èmi óo fi igbagbọ mi hàn ọ́ nípa iṣẹ́ mi. Ìwọ gbàgbọ́ pé Ọlọrun kan ní ń bẹ. Ó dára bẹ́ẹ̀. Àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá gbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, ìbẹ̀rùbojo sì mú wọn. Ìwọ eniyan lásán! O fẹ́ ẹ̀rí pé igbagbọ ti kò ní iṣẹ́ ninu jẹ́ òkú? Nípa iṣẹ́ kọ́ ni Abrahamu baba wa fi gba ìdáláre, nígbà tí ó fa Isaaki ọmọ rẹ̀ lọ sí orí pẹpẹ ìrúbọ? O rí i pé igbagbọ ń farahàn ninu iṣẹ́ rẹ̀, ati pé iṣẹ́ rẹ̀ ni ó ṣe igbagbọ rẹ̀ ní àṣepé. Èyí ni ó mú kí Ìwé Mímọ́ ṣẹ tí ó sọ pé, “Abrahamu gba Ọlọrun gbọ́, Ọlọrun sì kà á sí olódodo.” A wá pè é ní ọ̀rẹ́ Ọlọrun. Ṣé ẹ wá rí i pé nípa iṣẹ́ ni eniyan fi ń gba ìdáláre, kì í ṣe nípa igbagbọ nìkan? Ṣebí bákan náà ni Rahabu aṣẹ́wó gba ìdáláre nípa iṣẹ́, nígbà tí ó ṣe àwọn amí ní àlejò, tí ó jẹ́ kí wọ́n bá ọ̀nà mìíràn pada lọ? Bí ara láìsí ẹ̀mí ti jẹ́ òkú, bẹ́ẹ̀ ni igbagbọ láìsí iṣẹ́. Ẹ̀yin ará mi, kí ọpọlọpọ yín má máa jìjàdù láti jẹ́ olùkọ́ni, kí ẹ mọ̀ pé ìdájọ́ ti àwa olùkọ́ni yóo le. Nítorí gbogbo wa ni à ń ṣe àṣìṣe ní ọ̀pọ̀ ìgbà. Bí ẹnikẹ́ni bá wà tí kò ṣi ọ̀rọ̀ sọ rí, a jẹ́ pé olúwarẹ̀ pé, ó lè kó gbogbo ara rẹ̀ níjàánu. Tí a bá fi ìjánu sí ẹṣin lẹ́nu, kí wọ́n lè ṣe bí a ti fẹ́, a máa darí gbogbo ara wọn bí a bá ti fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo àwọn ọkọ̀ ojú omi. Bí wọ́n ti tóbi tó, tí ó jẹ́ pé afẹ́fẹ́ líle ní ń gbé wọn kiri, sibẹ ìtukọ̀ kékeré ni ọ̀gá àwọn atukọ̀ fi ń darí wọn sí ibi tí ó bá fẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni ahọ́n, ẹ̀yà ara kékeré ni, ṣugbọn ìhàlẹ̀ rẹ̀ pọ̀. Ẹ wo bírà tí iná kékeré lè dá ninu igbó ńlá! Iná ni ahọ́n. Ó kún fún àwọn nǹkan burúkú ayé yìí. Ninu àwọn ẹ̀yà ara wa, ahọ́n ni ó ń kó nǹkan ibi bá gbogbo ara. A máa mú kí gbogbo ara wá gbóná, iná ọ̀run àpáàdì ni ó túbọ̀ ń fún un ní agbára. Gbogbo ẹ̀dá pátá: ati ẹranko ni, ati ẹyẹ, ati àwọn ohun tí ń fàyà fà, ati àwọn ẹran omi, gbogbo wọn ni eniyan lè so lójú rọ̀. Ṣugbọn kò sí ẹnìkan tí ó kápá ahọ́n. Nǹkan burúkú tí ó kanpá ni, ó kún fún oró tí ó lè paniyan kíákíá. Ahọ́n ni a fi ń yin Oluwa ati Baba. Òun kan náà ni a fi ń ṣépè fún eniyan tí a dá ní àwòrán Ọlọrun. Láti inú ẹnu kan náà ni ìyìn ati èpè ti ń jáde. Ẹ̀yin ará mi, kò yẹ kí èyí rí bẹ́ẹ̀. Ǹjẹ́ omi dídùn ati omi kíkorò lè ti inú orísun omi kan náà jáde? Ẹ̀yin ará mi, ṣé igi ọ̀pọ̀tọ́ lè so èso olifi, tabi kí àjàrà kó so ọ̀pọ̀tọ́? Ìsun omi kíkorò kò lè mú omi dídùn jáde. Ẹnikẹ́ni wà láàrin yín tí ó gbọ́n, tí ó tún mòye? Kí ó fihàn nípa ìgbé-ayé rere ati ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tí ó fi ọgbọ́n hàn. Ṣugbọn tí ẹ bá ń jowú ara yín kíkankíkan, tí ẹ ní ọkàn ìmọ-tara-ẹni-nìkan, ẹ má máa gbéraga, kí ẹ má sì purọ́ mọ́. Èyí kì í ṣe ọgbọ́n tí ó wá láti òkè, ọgbọ́n ayé ni, gẹ́gẹ́ bíi ti ẹran-ara, ati ti ẹ̀mí burúkú. Níbi tí owú ati ìlara bá wà, ìrúkèrúdò ati oríṣìíríṣìí ìwà burúkú a máa wà níbẹ̀. Ṣugbọn ní àkọ́kọ́, ọgbọ́n tí ó ti òkè wá jẹ́ pípé, lẹ́yìn náà a máa mú alaafia wá, a máa ṣe ẹ̀tọ́, a máa ro ọ̀rọ̀ dáradára, a máa ṣàánú; a máa so èso rere, kì í ṣe ẹnu meji, kì í ṣe àgàbàgebè. Àwọn tí wọn bá ń fúnrúgbìn ire pẹlu alaafia yóo kórè alaafia. Níbo ni ogun ti ń wá? Níbo ni ìjà sì ti ń wá sáàrin yín? Ṣebí nípa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yín tí ó ń jagun ninu àwọn ẹ̀yà ara yín ni. Ẹ̀ ń fẹ́ nǹkankan, ọwọ́ yín kò sì tẹ̀ ẹ́; ẹ bá ń tìtorí rẹ̀ paniyan; ẹ̀ ń jowú nítorí nǹkankan, ọwọ́ yín kò bá ohun tí ẹ̀ ń jowú lé lórí, ẹ bá sọ ọ́ di ọ̀ràn ìjà ati ogun. Ọwọ́ yín kò tẹ ohun tí ẹ fẹ́ nítorí pé ẹ kò bèèrè lọ́dọ̀ Ọlọrun. Bí ẹ bá sì bèèrè, ẹ kò rí ohun tí ẹ bèèrè gbà nítorí èrò burúkú ni ẹ fi bèèrè, kí ẹ lè lo ohun tí ẹ bèèrè fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara yín. Ẹ̀yin àgbèrè, ẹ kò mọ̀ pé ìbá ayé ṣọ̀rẹ́ níláti jẹ́ ìbá Ọlọrun ṣọ̀tá? Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé ti yàn láti jẹ́ ọ̀tá Ọlọrun. Àbí ẹ rò pé lásán ni Ìwé Mímọ́ sọ pé, “Ẹ̀mí tí ó fi sinu wa ń jowú gidigidi lórí wa?” Ṣugbọn oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fi fúnni tóbi ju èyí lọ. Nítorí èyí ni Ìwé Mímọ́ ṣe sọ pé, “Ọlọrun lòdì sí àwọn onigbeeraga, ṣugbọn ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.” Nítorí náà, ẹ fi ara yín sábẹ́ àṣẹ Ọlọrun. Ẹ dojú ìjà kọ Èṣù, yóo sì sálọ kúrò lọ́dọ̀ yín. Ẹ súnmọ́ Ọlọrun, òun óo sì súnmọ́ yín. Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹ jẹ́ kí ọkàn yín dá ṣáká, ẹ̀yin oníyèméjì. Ẹ jẹ́ kí ọkàn yín bàjẹ́, ẹ ṣọ̀fọ̀, ẹ sọkún; ẹ má rẹ́rìn-ín mọ́, ńṣe ni kí ẹ fajúro. Ẹ máa banújẹ́ dípò yíyọ̀ tí ẹ̀ ń yọ̀. Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ níwájú Oluwa, yóo wá gbe yín ga. Ẹ̀yin ará, ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ àbùkù nípa ara yín. Ẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ àbùkù nípa arakunrin rẹ̀ tabi tí ó bá ń dá arakunrin rẹ̀ lẹ́jọ́ ń sọ̀rọ̀ àbùkù sí òfin, ó tún ń dá òfin lẹ́jọ́. Tí ó bá wá ń dá òfin lẹ́jọ́, ó sọ ara rẹ̀ di onídàájọ́ òfin dípò olùṣe ohun tí òfin wí. Ẹnìkan ṣoṣo ni ó fúnni lófin, tí ó jẹ́ onídàájọ́. Òun ni ẹni tí ó lè gba ẹ̀mí là, tí ó sì lè pa ẹ̀mí run; Ṣugbọn ìwọ, ta ni ọ́ tí o fi ń dá ẹnìkejì rẹ lẹ́jọ́? Ẹ gbọ́ ná, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wí pé, “Lónìí, tabi lọ́la, a óo lọ sí ibi báyìí, a óo ṣe ọdún kan níbẹ̀; a óo ṣòwò, a óo sì jèrè.” Ẹ kò mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ si yín lọ́la. Nítorí ìkùukùu ni yín, tí ó wà fún àkókò díẹ̀, lẹ́yìn náà tí kò ní sí mọ́. Ohun tí ẹ̀ bá máa wí ni pé “Bí Oluwa bá dá ẹ̀mí sí, a óo ṣe báyìí báyìí.” Ṣugbọn ẹ̀ ń lérí, ẹ̀ ń fọ́nnu; irú ìlérí báyìí kò dára. Nítorí náà, ẹni tí ó bá mọ rere í ṣe tí kò ṣe é, ẹ̀ṣẹ̀ ni ó ń gbà. Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọlọ́rọ̀. Ẹ máa sọkún, kí ẹ sì máa ké gidi nítorí ìṣẹ́ tí ó ń bọ̀ wá ṣẹ́ yín. Ọrọ̀ yín ti bàjẹ́. Kòkòrò ti jẹ gbogbo aṣọ yín. Wúrà yín ati fadaka yín ti dógùn-ún. Dídógùn-ún wọn ni yóo jẹ́ ẹ̀rí fun yín, nítorí yóo jẹ ara yín bí ìgbà tí iná bá ń jó nǹkan. Inú ayé tí ó fẹ́rẹ̀ dópin ni ẹ̀ ń to ìṣúra jọ sí! Owó iṣẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ṣiṣẹ́ ní oko yín, tí ẹ kò san fún wọn ń pariwo yín. Igbe àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ba yín kórè oko yín sì ti dé etí Oluwa Ọlọrun Olodumare. Ẹ̀ ń ṣe fàájì ninu ayé, ẹ̀ ń jẹ, ẹ̀ ń mu. Ẹ wá sanra bíi mààlúù, bẹ́ẹ̀ sì ni ọjọ́ tí wọn yóo dumbu mààlúù ló kù sí dẹ̀dẹ̀ yìí. Ẹ gbé ẹ̀bi fún aláre, ẹ sì pa á, kò lè rú pútú. Ẹ̀yin ará, ẹ mú sùúrù títí Oluwa yóo fi dé. Ẹ wo àgbẹ̀ tí ó ń retí èso tí ó dára ninu oko, ó níláti mú sùúrù fún òjò àkọ́rọ̀ ati òjò àrọ̀kẹ́yìn. Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin gan-an mú sùúrù. Ẹ ṣe ọkàn yín gírí, nítorí Oluwa fẹ́rẹ̀ dé. Ẹ̀yin ará, ẹ má ṣe bá ara yín wí, kí á má baà da yín lẹ́jọ́. Onídàájọ́ ti dúró lẹ́nu ọ̀nà. Ẹ̀yin ará, ẹ wo àpẹẹrẹ àwọn wolii, àwọn tí wọ́n sọ̀rọ̀ ní orúkọ Oluwa pẹlu sùúrù ninu ọpọlọpọ ìpọ́njú. Ẹ ranti pé àwọn tí ó bá ní ìfaradà ni à ń pè ní ẹni ibukun. Ẹ ti gbọ́ nípa Jobu, bí ó ti ní ìfaradà, ẹ sì mọ bí Oluwa ti jẹ́ kí ó yọrí sí fún un. Nítorí oníyọ̀ọ́nú ati aláàánú ni Oluwa. Boríborí gbogbo rẹ̀, ẹ̀yin ará mi, ẹ má máa búra, ìbáà ṣe pé kí ẹ fi ọ̀run búra, tabi ilẹ̀, tabi ohun mìíràn. Tí ẹ bá wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni,” bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ó jẹ́. Bí ẹ bá wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́,” kí ó jẹ́ “Bẹ́ẹ̀ kọ́.” Kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdájọ́. Bí ẹnikẹ́ni ninu yín bá wà ninu ìyọnu, kí olúwarẹ̀ gbadura. Bí inú ẹnikẹ́ni ninu yín bá dùn, kí olúwarẹ̀ máa kọ orin ìyìn. Bí ẹnikẹ́ni ninu yín bá ń ṣàìsàn, kí ó pe àwọn àgbà ìjọ jọ, kí wọ́n gbadura fún un, kí wọ́n fi òróró pa á lára ní orúkọ Oluwa. Adura pẹlu igbagbọ yóo mú kí ara aláìsàn náà yá. Oluwa yóo gbé e dìde, a óo sì dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá jì í. Ẹ máa jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín fún ara yín, ẹ máa gbadura fún ara yín kí ẹ lè ní ìwòsàn. Adura àtọkànwá olódodo lágbára, nítorí Ọlọrun a máa fi àṣẹ sí i. Eniyan ẹlẹ́ran-ara bí àwa ni Elija. Ó fi tọkàntọkàn gbadura pé kí òjò má rọ̀. Òjò kò sì rọ̀ sórí ilẹ̀ fún odidi ọdún mẹta ati oṣù mẹfa. Ó tún gbadura, òjò sì rọ̀ sórí ilẹ̀ láti òkè, ilẹ̀ sì hu ohun ọ̀gbìn jáde. Ẹ̀yin ará mi, bí ẹnikẹ́ni ninu yín bá ṣìnà kúrò ninu òtítọ́, tí ẹnìkan bá tọ́ ọ sọ́nà, ẹ mọ̀ dájú pé ẹni tí ó bá mú ẹlẹ́ṣẹ̀ pada kúrò ninu ìṣìnà rẹ̀ gba ọkàn ẹni náà lọ́wọ́ ikú, ó sì mú kí ìgbàgbé bá ọpọlọpọ ẹ̀ṣẹ̀. Èmi Peteru, aposteli Jesu Kristi ni mò ń kọ ìwé yìí sí ẹ̀yin tí ẹ fọ́n káàkiri àwọn ìlú àjèjì bíi Pọntu, Galatia, Kapadokia, Esia ati Bitinia. Ẹ̀yin ni a yàn gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọrun Baba fún ìwà mímọ́ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ kí ẹ lè máa gbọ́ ti Jesu Kristi, kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì lè wẹ̀ yín mọ́. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia kí ó pọ̀ fun yín. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, Baba Jesu Kristi Oluwa wa, tí ó fi ọ̀pọ̀ àánú rẹ̀ tún wa bí sí ìrètí tí ó wà láàyè nípa ajinde Jesu Kristi kúrò ninu òkú. Ó fún wa ni ogún ainipẹkun, ogún tí kò lè díbàjẹ́, tí kò lè ṣá, tí a ti fi pamọ́ fun yín ní ọ̀run. Ẹ̀yin ni a ti dáàbò bò nípa agbára Ọlọrun nípa igbagbọ sí ìgbàlà tí a ti ṣe ètò láti fihàn ní ọjọ́ ìkẹyìn. Ẹ máa yọ̀ nítorí èyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé fún àkókò díẹ̀, ẹ níláti ní ìdààmú nípa oríṣìíríṣìí ìdánwò. Wúrà níláti kọjá ninu iná, bẹ́ẹ̀ sì ni ó pẹ́ ni, ó yá ni, yóo ṣègbé. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni a níláti dán igbagbọ yín tí ó ní iye lórí ju wúrà lọ wò. Irú igbagbọ bẹ́ẹ̀ yóo gba ìyìn, ògo, ati ọlá nígbà tí Jesu Kristi bá dé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò rí i, sibẹ ẹ fẹ́ràn rẹ̀. Ẹ kò rí i sójú nisinsinyii, sibẹ ẹ gbà á gbọ́, ẹ sì ń yọ ayọ̀ tí ẹnu kò lè sọ, ayọ̀ tí ó lógo, nítorí pé ẹ jèrè igbagbọ yín nípa ìgbàlà ọkàn yín. Àwọn wolii tí wọ́n ṣe ìkéde oore-ọ̀fẹ́ tún fẹ̀sọ̀ wádìí nípa ìgbàlà yìí. Wọ́n ń wádìí nípa ẹni náà ati àkókò náà, tí Ẹ̀mí Kristi tí ó wà ninu wọn ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìyà tí Kristi níláti jẹ, ati bí yóo ti ṣe bọ́ sinu ògo lẹ́yìn ìjìyà rẹ̀. Ọlọrun fihan àwọn wolii wọnyi pé ohun tí wọn ń sọ kì í ṣe fún àkókò tiwọn bíkòṣe fún àkókò tiyín. Nisinsinyii a ti waasu nǹkan wọnyi fun yín nípa ìyìn rere tí ó ti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ wá, tí a rán láti ọ̀run wá fun yín. Àwọn angẹli garùn títí láti rí nǹkan wọnyi. Nítorí náà, ẹ ṣe ọkàn yìn gírí. Ẹ máa ṣe pẹ̀lẹ́. Ẹ máa retí oore-ọ̀fẹ́ tí yóo jẹ́ tiyín nígbà tí Jesu Kristi bá tún dé. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ tí ń gbọ́ràn, ẹ má gbé irú ìgbé-ayé yín ti àtijọ́, nígbà tí ẹ̀ ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara yín tí ẹ kò mọ̀ pé àìdára ni. Ṣugbọn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó pè yín ti jẹ́ mímọ́, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin náà jẹ́ mímọ́ ninu gbogbo ìwà yín. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, Ọlọrun ní, “Ẹ jẹ́ mímọ́, nítorí èmi náà jẹ́ mímọ́.” Níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀ ń pe Ọlọrun ní Baba tí kì í ṣe ojuṣaaju, tí ó jẹ́ pé bí iṣẹ́ olukuluku bá ti rí ní ó fi ń ṣe ìdájọ́, ẹ máa fi ìbẹ̀rù gbé ìgbé-ayé yín ní ìwọ̀nba àkókò tí ẹ ní. Nítorí ẹ mọ̀ pé kì í ṣe ohun tí ó lè bàjẹ́, bíi fadaka ati wúrà, ni a fi rà yín pada kúrò ninu ìgbé-ayé asán tí ẹ jogún láti ọ̀dọ̀ àwọn baba yín. Ohun tí a fi rà yín ni ẹ̀jẹ̀ Kristi, ẹ̀jẹ̀ iyebíye bíi ti ọ̀dọ́-aguntan tí kò ní àléébù, tí kò sì ní àbààwọ́n. Kí á tó dá ayé ni a ti yan Kristi fún iṣẹ́ yìí. Ṣugbọn ní àkókò ìkẹyìn yìí ni ó tó fi ara hàn nítorí tiyín. Ẹ̀yin tí ẹ ti ipasẹ̀ rẹ̀ gba Ọlọrun tí ó jí i dìde kúrò ninu òkú gbọ́, tí ó ṣe é lógo, kí igbagbọ ati ìrètí yín lè wà ninu Ọlọrun. Níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti wẹ ọkàn yín mọ́ nípa ìgbọràn sí òtítọ́, tí ẹ sì ní ìfẹ́ àìlẹ́tàn sí àwọn onigbagbọ ara yín, ẹ fi tinútinú fẹ́ràn ọmọnikeji yín. A ti tún yín bí! Kì í ṣe èso tí ó lè bàjẹ́ ni a fi tún yín bí bíkòṣe èso tí kò lè bàjẹ́, tíí ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí ó wà láàyè, tí ó sì wà títí. Nítorí, “Gbogbo ẹlẹ́ran-ara dàbí Koríko, gbogbo ògo rẹ̀ dàbí òdòdó. Koríko a máa gbẹ, òdòdó a máa rẹ̀, ṣugbọn ọ̀rọ̀ Oluwa yóo wà títí lae.” Òun ni ọ̀rọ̀ tí à ń waasu rẹ̀ fun yín. Nítorí náà, ẹ pa gbogbo ìwà ibi tì, ati ọgbọ́n ẹ̀wẹ́, àgàbàgebè, owú jíjẹ ati ọ̀rọ̀ àbùkù. Ẹ ṣe bí ọmọ-ọwọ́ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, tí òùngbẹ wàrà gidi ti ẹ̀mí ń gbẹ, kí ó lè mu yín dàgbà fún ìgbàlà. Ó ṣá ti hàn si yín pé olóore ni Oluwa. Ẹ wá sọ́dọ̀ ẹni tíí ṣe òkúta ààyè tí eniyan kọ̀ sílẹ̀ ṣugbọn tí Ọlọrun yàn, tí ó ṣe iyebíye lójú rẹ̀. Ẹ fi ara yín kọ́ ilé ẹ̀mí bí òkúta ààyè, níbi tí ẹ óo jẹ́ alufaa mímọ́, tí ẹ óo máa rú ẹbọ ẹ̀mí tí Ọlọrun yóo tẹ́wọ́ gbà nípasẹ̀ Jesu Kristi. Nítorí ó wà ninu Ìwé Mímọ́ pé, “Mo fi òkúta lélẹ̀ ní Sioni, àṣàyàn òkúta igun ilé tí ó ṣe iyebíye. Ojú kò ní ti ẹni tí ó bá gbà á gbọ́.” Nítorí náà, ọlá ni fún ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́. Ṣugbọn fún àwọn tí kò gbàgbọ́, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí, “Òkúta tí àwọn mọlémọlé kọ̀ sílẹ̀, òun ni ó di pataki igun ilé.” Ati, “Òkúta tí yóo mú eniyan kọsẹ̀, ati àpáta tí yóo gbé eniyan ṣubú.” Àwọn tí ó ṣubú ni àwọn tí kò gba ọ̀rọ̀ náà gbọ́. Bẹ́ẹ̀, bí ti irú wọn ti níláti rí nìyí. Ṣugbọn ẹ̀yin ni orílẹ̀-èdè tí Ọlọrun yàn, alufaa ọlọ́lá, ẹ̀yà mímọ́, eniyan tí Ọlọrun ṣe ní tirẹ̀, kí ẹ lè sọ àwọn iṣẹ́ ńlá tí ẹni tí ó pè yín láti inú òkùnkùn sí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tí ó yani lẹ́nu. Ẹ̀yin tí ẹ kì í ṣe eniyan nígbà kan, ṣugbọn nisinsinyii ẹ di eniyan Ọlọrun. Ẹ̀yin tí ẹ kò tíì rí àánú gbà tẹ́lẹ̀ ṣugbọn nisinsinyii ẹ di ẹni tí Ọlọrun ṣàánú fún. Ẹ̀yin olùfẹ́ tí ẹ jẹ́ àlejò ní ilẹ̀ àjèjì, mo bẹ̀ yín, ẹ jìnnà sí àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara tí ó ń bá ọkàn jagun. Kí ìgbé-ayé yín láàrin àwọn abọ̀rìṣà jẹ́ èyí tí ó dára, tí ó fi jẹ́ pé bí wọ́n bá tilẹ̀ ń sọ̀rọ̀ yín ní àìdára, sibẹ nígbà tí wọ́n bá ṣe akiyesi ìwà rere yín, wọn yóo yin Ọlọrun lógo ní ọjọ́ ìdájọ́. Ẹ fi ara yín sábẹ́ òfin ìjọba ilẹ̀ yín nítorí ti Oluwa, ìbáà ṣe ọba gẹ́gẹ́ bí olórí, tabi aṣojú ọba gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó rán láti jẹ àwọn tí ó bá ń ṣe burúkú níyà, ati láti yin àwọn tí ó bá ń ṣe rere. Nítorí bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ Ọlọrun pé nípa ìwà rere yín, kí kẹ́kẹ́ pamọ́ àwọn aṣiwèrè ati àwọn òpè lẹ́nu. Ẹ máa hùwà bí ẹni tí ó ní òmìnira, ṣugbọn kì í ṣe òmìnira láti bo ìwà burúkú mọ́lẹ̀. Ẹ máa hùwà bí iranṣẹ Ọlọrun. Ẹ máa yẹ́ gbogbo eniyan sí. Ẹ máa fẹ́ràn àwọn onigbagbọ. Ẹ bẹ̀rù Ọlọrun. Ẹ máa bu ọlá fún ọba. Ẹ̀yin ọmọ-ọ̀dọ̀, ẹ máa bọ̀wọ̀ fún àwọn ọ̀gá yín ninu gbogbo nǹkan pẹlu ìbẹ̀rù, kì í ṣe fún àwọn ọ̀gá tí ó ní inú rere, tí wọ́n sì ń ṣe ẹ̀tọ́ si yín nìkan, ṣugbọn fún àwọn tí wọ́n rorò pẹlu. Nítorí ó dára kí eniyan farada ìyà tí kò tọ́ sí i tí ó bá ronú ti Ọlọrun. Nítorí ẹ̀yẹ wo ni ó wà ninu pé ẹ ṣe àìdára, wọ́n lù yín, ẹ wá faradà á? Ṣugbọn tí ẹ bá ń ṣe dáradára, tí ẹ jìyà tí ẹ faradà á, èyí jẹ́ ẹ̀yẹ lójú Ọlọrun. Nítorí ìdí èyí ni a fi pè yín, nítorí Kristi jìyà nítorí yín, ó fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fun yín, pé kí ẹ tẹ̀lé àpẹẹrẹ òun. Ẹni tí kò dẹ́ṣẹ̀, tí a kò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ní ẹnu rẹ̀ rí. Nígbà tí àwọn eniyan kẹ́gàn rẹ̀, kò désì pada; wọ́n jẹ ẹ́ níyà, kò ṣe ìlérí ẹ̀san, ṣugbọn ó fi ọ̀ràn rẹ̀ lé Onídàájọ́ òdodo lọ́wọ́. Òun fúnrarẹ̀ ni ó ru ẹ̀ṣẹ̀ wa lórí igi, kí á baà lè kú sí ẹ̀ṣẹ̀, kí á wà láàyè sí òdodo. Nípa ìnà rẹ̀ ni ẹ fi ní ìmúláradá. Nítorí pé nígbà kan ẹ dàbí aguntan tí ó sọnù. Ṣugbọn nisinsinyii ẹ ti yipada sí olùṣọ́ yín ati alabojuto ọkàn yín. Bákan náà ni kí ẹ̀yin aya máa bọ̀wọ̀ fún àwọn ọkọ yín. Ìdí rẹ̀ ni pé bí a bá rí ninu àwọn ọkọ tí kò jẹ́ onigbagbọ, wọ́n lè yipada nípa ìwà ẹ̀yin aya wọn láìjẹ́ pé ẹ bá wọn sọ gbolohun kan nípa ẹ̀sìn igbagbọ, nígbà tí wọ́n bá ṣe akiyesi ìwà mímọ́ ati ìwà ọmọlúwàbí yín. Ẹwà yín kò gbọdọ̀ jẹ́ ti òde ara nìkan bíi ti irun-dídì, ati nǹkan ọ̀ṣọ́ wúrà tí ẹ kó sára ati aṣọ-ìgbà. Ṣugbọn kí ẹwà yín jẹ́ ti ọkàn tí kò hàn sóde, ọkàn ìrẹ̀lẹ̀ ati ìwà pẹ̀lẹ́. Èyí ni ẹwà tí kò lè ṣá, èyí tí ó ṣe iyebíye lójú Ọlọrun. Nítorí ní ìgbà àtijọ́ irú ẹwà báyìí ni àwọn aya tí a yà sọ́tọ̀, àwọn tí wọ́n ní ìrètí ninu Ọlọrun, fi ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́. Wọ́n bọ̀wọ̀ fún ọkọ wọn. Irú wọn ni Sara tí ó gbọ́ràn sí Abrahamu lẹ́nu tí ó pè é ní “Oluwa mi.” Ọmọ Sara ni yín, tí ẹ bá ń ṣe dáradára, tí ẹ kò jẹ́ kí nǹkankan bà yín lẹ́rù tabi kí ó mú ìpayà ba yín. Kí ẹ̀yin ọkọ náà máa fi ọgbọ́n bá àwọn aya yín gbé. Ẹ máa bu ọlá fún wọn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí kò lágbára to yín. Ẹ ranti pé wọ́n jẹ́ alábàápín ẹ̀bùn ìyè pẹlu yín. Tí ẹ bá ń ṣe èyí, kò ní sí ìdènà ninu adura yín. Ní gbolohun kan, ẹ ní inú kan sí ara yín. Ẹ ni ojú àánú. Ẹ ní ìfẹ́ sí ara yín. Ẹ máa ṣoore. Ẹ ní ọkàn ìrẹ̀lẹ̀. Ẹ má fi burúkú gbẹ̀san burúkú, tabi kí ẹ fi àbùkù kan ẹni tí ó bá fi àbùkù kàn yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa sọ̀rọ̀ wọn ní rere ni. Irú ìwà tí a ní kí ẹ máa hù nìyí, kí ẹ lè jogún ibukun tí Ọlọrun ṣèlérí fun yín. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ẹni tí ó bá fẹ́ ìgbé-ayé tí ó wù ú, tí ó fẹ́ rí ọjọ́ tí ó dára, ó níláti kó ara rẹ̀ ni ìjánu pẹlu ọ̀rọ̀ burúkú sísọ, kí ó má fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn. Ó níláti yipada kúrò ninu ìwà burúkú, kí ó máa hu ìwà rere. Ó níláti máa wá alaafia, kí ó sì máa lépa rẹ̀. Nítorí Oluwa ń ṣọ́ àwọn olódodo, ó sì dẹ etí sí ẹ̀bẹ̀ wọn. Ṣugbọn ojú Oluwa kan sí àwọn tí ó ń ṣe burúkú.” Ta ni lè ṣe yín ní ibi tí ẹ bá ní ìtara fún ohun tíí ṣe rere? Ṣugbọn bí ẹ bá tilẹ̀ jìyà nítorí òdodo, ẹ ṣe oríire. Ẹ má bẹ̀rù àwọn tí wọn ń jẹ yín níyà, kí ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín dàrú. Ṣugbọn ẹ fi ààyè fún Kristi ninu ọkàn yín bí Oluwa. Ẹ múra nígbà gbogbo láti dáhùn bí ẹnikẹ́ni bá bi yín ní ìbéèrè nípa ìrètí tí ẹ ní. Ṣugbọn kí ẹ dáhùn pẹlu ìrẹ̀lẹ̀ ati ìwà pẹ̀lẹ́. Ẹ ní ẹ̀rí ọkàn tí ó mọ́, tí ó fi jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá ń sọ ọ̀rọ̀ yín ní àìdára, ojú yóo ti àwọn tí wọn ń sọ̀rọ̀ àbùkù nípa yín, nígbà tí wọn bá rí ìgbé-ayé yín gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ. Nítorí ó sàn fun yín tí ó bá jẹ́ ìfẹ́ Ọlọrun pé kí ẹ jìyà, nítorí pé ẹ̀ ń ṣe rere, jù pé ẹ̀ ń ṣe ibi lọ. Nítorí Kristi kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo fún ẹ̀ṣẹ̀ wa; olódodo ni, ó kú fún alaiṣododo, kí ó lè mú wa wá sọ́dọ̀ Ọlọrun. A pa á ní ti ara, ṣugbọn ó wà láàyè ní ti ẹ̀mí. Nípa ẹ̀mí, ó lọ waasu fún àwọn ẹ̀mí tí ó wà lẹ́wọ̀n. Àwọn wọnyi ni ẹ̀mí àwọn ẹni tí kò gbàgbọ́ nígbà kan rí, nígbà ayé Noa, nígbà tí Ọlọrun ninu àánú rẹ̀ mú sùúrù tí Noa fi kan ọkọ̀ tán. Ninu ọkọ̀ yìí ni àwọn eniyan díẹ̀ wà, àwọn mẹjọ, tí a fi gbà wọ́n là ninu ìkún omi. Èyí jẹ́ àkàwé ìrìbọmi tí ó ń gba eniyan là nisinsinyii. Kì í ṣe láti wẹ ìdọ̀tí kúrò lára, bíkòṣe ọ̀nà tí ẹ̀bẹ̀ eniyan fi lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọrun nípa ẹ̀rí ọkàn rere, nípa ajinde Jesu Kristi, ẹni tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun, tí ó ti kọjá lọ sọ́run, lẹ́yìn tí àwọn angẹli ati àwọn aláṣẹ ati àwọn alágbára ojú ọ̀run ti wà ní ìkáwọ́ rẹ̀. Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí Kristi ti jìyà ninu ara, kí ẹ̀yin náà di ọkàn yín ní àmùrè láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí ẹni tí ó bá jìyà nípa ti ara ti bọ́ lọ́wọ́ agbára ẹ̀ṣẹ̀. Má tún máa ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀dá mọ́, ṣugbọn máa ṣe ìfẹ́ Ọlọrun ninu gbogbo ìgbé-ayé rẹ tí ó kù. Ní ìgbà kan rí ẹ ní anfaani tó láti ṣe àwọn ohun tí àwọn abọ̀rìṣà ń ṣe. Ẹ̀ ń hùwà wọ̀bìà, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ìmutípara, ayé ìjẹkújẹ, ìmukúmu ati ìbọ̀rìṣà tí ó jẹ́ èèwọ̀. Nisinsinyii ó jẹ́ ohun ìjọjú fún àwọn ẹlẹgbẹ́ yín àtijọ́, nígbà tí ẹ kò bá wọn lọ́wọ́ sí ayé ìjẹkújẹ mọ́, wọn óo wá máa fi yín ṣe ẹlẹ́yà. Ṣugbọn wọn óo dáhùn fún ìwà wọn níwájú ẹni tí ó ṣetán láti ṣe ìdájọ́ alààyè ati òkú. Nítorí rẹ̀ ni a ṣe waasu ìyìn rere fún àwọn òkú, pé bí wọ́n bá tilẹ̀ gba ìdájọ́ bí gbogbo eniyan ti níláti gbà ninu ara, sibẹ wọn óo wà láàyè ninu ẹ̀mí nípa ti Ọlọrun. Òpin ohun gbogbo súnmọ́ tòsí. Nítorí náà ẹ fi òye ati ìwà pẹ̀lẹ́ gbé ìgbé-ayé yín ninu adura. Ju ohun gbogbo lọ, ẹ ní ìfẹ́ tí ó jinlẹ̀ sí ara yín, nítorí ìfẹ́ bo ọpọlọpọ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀. Ẹ lawọ́ sí ara yín láìní ìkùnsínú. Olukuluku yín ní ẹ̀bùn tirẹ̀. Ẹ máa lo ẹ̀bùn yín fún ire ọmọnikeji yín, gẹ́gẹ́ bí ìríjú oríṣìíríṣìí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun. Bí ẹnikẹ́ni bá ń sọ̀rọ̀, kí ó mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Ọlọrun ni òun ń sọ. Bí ẹnikẹ́ni bá ṣe iṣẹ́ iranṣẹ, kí ó ṣe é pẹlu gbogbo agbára tí Ọlọrun fún un. Ninu ohun gbogbo ẹ máa hùwà kí ògo lè jẹ́ ti Ọlọrun nípasẹ̀ Jesu Kristi: òun ni ògo ati agbára jẹ́ tirẹ̀ lae ati laelae. Amin. Ẹ̀yin olùfẹ́ mi, ẹ má jẹ́ kí ó jọ yín lójú bí wọ́n bá wa iná jó yín láti dán yín wò, bí ẹni pé ohun tí ojú kò rí rí ni ó dé. Èyí sọ yín di alábàápín ninu ìjìyà Kristi. Ẹ máa yọ̀. Nígbà tí ó bá pada dé ninu ògo rẹ̀, ayọ̀ ńlá ni ẹ óo yọ̀. Bí wọn bá ń fi yín ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí orúkọ Kristi, ẹ ṣe oríire, nítorí Ẹ̀mí tí ó lógo nnì, Ẹ̀mí Ọlọrun, ti bà lé yín lórí. Tí ẹ bá níláti jìyà, kí ó má jẹ́ gẹ́gẹ́ bí apànìyàn, tabi olè, tabi eniyan burúkú, tabi ẹni tí ń tojú bọ nǹkan-oní-nǹkan. Ṣugbọn bí ẹ bá jìyà gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ ẹ má jẹ́ kí ó tì yín lójú, kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa yin Ọlọrun lógo fún orúkọ tí ẹ̀ ń jẹ́. Nítorí ó tó àkókò tí ìdájọ́ yóo bẹ̀rẹ̀, láàrin ìdílé Ọlọrun ni yóo sì ti bẹ̀rẹ̀. Tí ó bá wá bẹ̀rẹ̀ lọ́dọ̀ wa, báwo ni yóo ti rí fún àwọn tí kò gba ìyìn rere Ọlọrun gbọ́? Tí ó bá jẹ́ pé pẹlu agbára káká ni olódodo yóo fi là, báwo ni yóo ti rí fún àwọn tí kò bọ̀wọ̀ fún Ọlọrun ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀? Nítorí náà, kí àwọn tí ó ń jìyà nípa ìfẹ́ Ọlọrun fi ọkàn wọn fún Ọlọrun nípa ṣíṣe rere. Ọlọrun Ẹlẹ́dàá kò ní dójú tì wọ́n. Nítorí náà, mo bẹ àwọn àgbà láàrin yín, alàgbà ni èmi náà, ati ẹlẹ́rìí ìyà Kristi, n óo sì ní ìpín ninu ògo tí yóo farahàn. Mo bẹ̀ yín pé kí ẹ ṣe ìtọ́jú ìjọ Ọlọrun tí ẹ wà ninu rẹ̀. Ẹ máa ṣe iṣẹ́ yín bí alabojuto. Kì í ṣe àfipáṣe ṣugbọn tinútinú bí Ọlọrun ti fẹ́. Ẹ má ṣe é nítorí ohun tí ẹ óo rí gbà níbẹ̀, ṣugbọn kí ẹ ṣe é pẹlu ìtara àtọkànwá. Ẹ má ṣe é bí ẹni tí ó fẹ́ jẹ́ aláṣẹ lórí àwọn tí ó wà lábẹ́ yín ṣugbọn ẹ ṣe é bí àpẹẹrẹ fún ìjọ. Nígbà tí Olú olùṣọ́-aguntan bá dé, ẹ óo gba adé ògo tí kì í ṣá. Bákan náà, ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ máa tẹríba fún àwọn àgbà. Gbogbo yín, ẹ gbé ọkàn ìrẹ̀lẹ̀ wọ̀, bí ẹ ti ń bá ara yín lò, nítorí, “Ọlọrun lòdì sí àwọn onigbeeraga, ṣugbọn a máa fi ojurere wo àwọn onírẹ̀lẹ̀.” Nítorí náà, ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ Ọlọrun tí ó lágbára, yóo gbe yín ga ní àkókò tí ó bá wọ̀. Ẹ kó gbogbo ìpayà yín tọ̀ ọ́ lọ, nítorí ìtọ́jú yín jẹ ẹ́ lógún. Ẹ ṣọ́ra. Ẹ dira yín gírí, Èṣù tíí ṣe ọ̀tá yín, ń rìn kiri bíi kinniun tí ń bú ramúramù, ó ń wá ẹni tí yóo pa jẹ. Ẹ takò ó pẹlu igbagbọ tí ó dúró gbọningbọnin. Kí ẹ mọ̀ pé àwọn onigbagbọ ẹgbẹ́ yín ń jẹ irú ìyà kan náà níwọ̀n ìgbà tí wọ́n wà ninu ayé. Ṣugbọn lẹ́yìn tí ẹ bá ti jìyà díẹ̀, Ọlọrun tí ó ní gbogbo oore-ọ̀fẹ́, òun tí ó pè yín sinu ògo rẹ̀ ayérayé nípasẹ̀ Kristi, yóo mu yín bọ̀ sípò, yóo fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, yóo fun yín ní agbára, yóo sì tún fi ẹsẹ̀ ìgbé-ayé yín múlẹ̀. Òun ni agbára wà fún laelae. Amin. Silifanu ni ó bá mi kọ ìwé kúkúrú yìí si yín. Mo ka Silifanu yìí sí arakunrin tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé. Mò ń rọ̀ yín, mo tún ń jẹ́rìí pé oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun tòótọ́ nìyí. Ẹ dúró lórí ohun tí mo kọ. Ìjọ tí Ọlọrun yàn, ẹlẹgbẹ́ yín tí ó wà ní Babiloni ki yín. Bẹ́ẹ̀ náà ni Maku, ọmọ mi. Ẹ fi ìfẹnukonu ìfẹ́ kí ara yín. Kí alaafia kí ó wà pẹlu gbogbo ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ ti Kristi. Èmi, Simoni Peteru iranṣẹ ati aposteli Jesu Kristi, ni mò ń kọ ìwé yìí sí àwọn tí wọn ní irú anfaani tí a níláti gbàgbọ́ bíi tiwa, nípa òdodo Ọlọrun wa ati ti Olùgbàlà wa Jesu Kristi. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia pọ̀ sí i fun yín nípa mímọ Ọlọrun ati Jesu Oluwa wa. Nípa agbára Ọlọrun tí kì í ṣe ti eniyan, ó ti fún wa ní ohun gbogbo tí yóo jẹ́ kí á gbé irú ìgbé-ayé tí ó dára ati ti ìwà-bí-Ọlọrun, nípa mímọ ẹni tí ó fi ògo ati ọlá rẹ̀ pè wá. Nípasẹ̀ èyí ni a ti gba àwọn ìlérí iyebíye tí ó tóbi jùlọ, tí ó fi jẹ́ pé ẹ ti di alábàápín ninu ìwà Ọlọrun, ẹ sì ti sá fún ìbàjẹ́ tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti mú wọ inú ayé. Nítorí èyí, kí ẹ ní ìtara láti fi ìwà ọmọlúwàbí kún igbagbọ yín, kí ẹ sì fi ìmọ̀ kún ìwà ọmọlúwàbí. Ẹ fi ìkóra-ẹni-níjàánu kún ìmọ̀, kí ẹ fi ìgboyà kún ìkóra-ẹni-níjàánu, kí ẹ sì fi ìfọkànsìn kún ìgboyà. Ẹ fi ìṣoore fún àwọn onigbagbọ kún ìfọkànsìn, kí ẹ sì fi ìfẹ́ kún ìṣoore fún àwọn onigbagbọ. Nítorí tí ẹ bá ní àwọn nǹkan wọnyi; tí wọn ń dàgbà ninu yín, ìgbé-ayé yín kò ní jẹ́ lásán tabi kí ó jẹ́ aláìléso ninu mímọ Jesu Kristi. Afọ́jú ni ẹni tí kò bá ní àwọn nǹkan wọnyi, olúwarẹ̀ kò ríran jìnnà, kò sì lè ronú ẹ̀yìn-ọ̀la. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti gbàgbé ìwẹ̀mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àtijọ́. Ẹ̀yin ará, ìdí rẹ̀ nìyí tí ẹ fi gbọdọ̀ túbọ̀ ní ìtara láti fi pípè tí a pè yín ati yíyàn tí a yàn yín hàn. Tí ẹ bá ń ṣe àwọn nǹkan wọnyi, ẹ kò ní kùnà. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ti ṣe ní ẹ̀tọ́ láti rìn gaara wọ ìjọba ayérayé ti Oluwa wa, ati Olùgbàlà Jesu Kristi. Nítorí náà ni mo ṣe pinnu pé n óo máa ran yín létí gbogbo nǹkan wọnyi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ti mọ̀ wọ́n, ẹ sì ti fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ninu òtítọ́ tí ẹ ti mọ̀. Nítorí mo kà á sí ẹ̀tọ́ mi, níwọ̀n ìgbà tí mo wà ninu àgọ́ ara yìí, láti ji yín ninu oorun nípa rírán yín létí. Nítorí mo mọ̀ pé láìpẹ́ n óo bọ́ àgọ́ ara mi sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Oluwa wa Jesu Kristi ti fihàn mí. Ṣugbọn mò ń làkàkà pé nígbà tí mo bá lọ tán, kí ẹ ní ohun tí ẹ óo fi máa ṣe ìrántí nǹkan wọnyi nígbà gbogbo. Kì í ṣe ìtàn àròsọ ni a gbójú lé nígbà tí a sọ fun yín nípa agbára ati wíwá Oluwa wa Jesu Kristi, ṣugbọn ẹlẹ́rìí ọlá ńlá rẹ̀ ni a jẹ́. Nítorí a rí i nígbà tí ó gba ọlá ati ògo lọ́dọ̀ Ọlọrun Baba, nígbà tí ó gbọ́ ohùn láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ọlá ati ògo yẹ fún, tí ó wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ ọmọ mi, inú mi dùn sí ọ.” Àwa fúnra wa gbọ́ ohùn yìí nígbà tí ó wá láti ọ̀run nítorí a wà pẹlu rẹ̀ lórí òkè mímọ́ nígbà náà. A tún rí ẹ̀rí tí ó dájú ninu àsọtẹ́lẹ̀ àwọn wolii, pé, kí ẹ ṣe akiyesi ọ̀rọ̀ yìí, nítorí ó dàbí fìtílà tí ń tàn ninu òkùnkùn, títí ilẹ̀ yóo fi mọ̀, títí ìràwọ̀ òwúrọ̀ yóo fi tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ sinu ọkàn yín. Ṣugbọn kí ẹ kọ́kọ́ mọ èyí pé, kò sí àsọtẹ́lẹ̀ kan ninu Ìwé Mímọ́ tí ẹnìkan lè dá túmọ̀. Nítorí kì í ṣe nípasẹ̀ ìfẹ́ ẹnikẹ́ni ni àsọtẹ́lẹ̀ kan fi wá, nípa Ẹ̀mí Mímọ́ ni àwọn eniyan fi ń sọ ọ̀rọ̀ tí ó ti ọ̀dọ̀ Oluwa wá. Ṣugbọn bí àwọn wolii èké ti dìde láàrin àwọn eniyan Israẹli, bẹ́ẹ̀ ni àwọn olùkọ́ni èké yóo wà láàrin yín. Wọn óo fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ mú ẹ̀kọ́kẹ́kọ̀ọ́ wọ ààrin yín. Wọn óo sẹ́ Oluwa wọn tí ó rà wọ́n pada, nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ wọn óo mú ìparun wá sórí ara wọn kíákíá. Ọpọlọpọ eniyan ni yóo bá wọn kẹ́gbẹ́ ninu ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn; nítorí ìṣe wọn, àwọn eniyan yóo máa gan ọ̀nà òtítọ́. Wọn óo fi ọ̀rọ̀ dídùn tàn yín nítorí ojúkòkòrò, kí wọ́n lè fi yín ṣe èrè jẹ. Ìdájọ́ tí ó wà lórí wọn láti ìgbà àtijọ́ kò parẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ìparun tí ń bọ̀ wá bá wọn kò sùn. Nítorí Ọlọrun kò dáríjì àwọn angẹli tí ó ṣẹ̀ ẹ́, ṣugbọn ó jù wọ́n sinu ọ̀gbun tí ó ṣókùnkùn biribiri ní ọ̀run àpáàdì títí di ọjọ́ ìdájọ́. Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun kò dáríjì àwọn ará àtijọ́, nígbà tí ó fi ìkún omi pa ayé run pẹlu àwọn tí wọn kò bẹ̀rù rẹ̀, àfi Noa, ọ̀kan ninu àwọn mẹjọ, tí ń waasu òdodo, ni ó gbà là. Bẹ́ẹ̀ tún ni ìlú Sodomu ati Gomora tí ó dá lẹ́bi, tí ó sì dáná sun. Èyí jẹ́ àpẹẹrẹ ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí kò bẹ̀rù Ọlọrun. Ṣugbọn ó yọ Lọti tí ó jẹ́ olódodo eniyan, tí ọkàn rẹ̀ bàjẹ́ nítorí ìwàkiwà àwọn tí ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn. Nítorí ohun tí ojú rẹ̀ ń rí ati ohun tí etí rẹ̀ ń gbọ́ ń ba ọkàn ọkunrin olódodo yìí jẹ́ lojoojumọ bí ó ti ń gbé ààrin àwọn eniyan burúkú yìí. Oluwa mọ ọ̀nà láti yọ àwọn olùfọkànsìn kúrò ninu ìdánwò, ṣugbọn ó pa àwọn alaiṣododo mọ́ de ìyà Ọjọ́ Ìdájọ́. Pàápàá jùlọ, yóo jẹ àwọn tí wọn ń tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn lọ́rùn níyà. Wọ́n ń fojú tẹmbẹlu àwọn aláṣẹ. Ògbójú ni wọ́n, ati onigbeeraga; wọn kò bẹ̀rù láti sọ ìsọkúsọ sí àwọn ogun ọ̀run. Nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn angẹli tí wọ́n ní agbára ati ipá ju eniyan lọ, kò jẹ́ sọ ìsọkúsọ sí wọn nígbà tí wọn bá ń mú wọn lọ fún ìdájọ́ Ọlọrun. Wọ́n dàbí ẹranko tí kò lè ronú, tí a bí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá, tí a mú, tí a pa. Wọn a máa sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ohun tí kò yé wọn. Ìparun yóo bá wọn ninu ọ̀nà ìparun wọn. Ibi ni wọn yóo jèrè lórí ibi tí wọn ń ṣe. Wọ́n ka ati máa ṣe àríyá ní ọ̀sán gangan sí ìgbádùn. Àbùkù ati ẹ̀gàn ni wọ́n láàrin yín. Ẹ̀tàn ni àríyá tí wọn ń ṣe nígbà tí ẹ bá jọ jókòó láti jẹun. Ojú wọn kún fún àgbèrè, kì í sinmi fún ẹ̀ṣẹ̀. Wọn a máa tan àwọn tí kò lágbára. Gbogbo ohun tí ó wà lórí ẹ̀mí wọn ni pé kí wọ́n ṣá rí owó lọ́nàkọnà. Ọmọ ègún ni wọ́n. Wọ́n fi ọ̀nà títọ́ sílẹ̀, wọ́n ń ṣe ránun-rànun kiri. Wọ́n tẹ̀lé ọ̀nà Balaamu ọmọ Beori, tí ó fẹ́ràn èrè aiṣododo. Ṣugbọn tí ó rí ìbáwí fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ẹranko tí kò lè fọhùn sọ̀rọ̀ bí eniyan, ó dí wolii náà lọ́wọ́ ninu ìwà aṣiwèrè rẹ̀. Wọ́n dàbí ìsun omi tí ó ti gbẹ, ati ìkùukùu tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kiri. Ọlọrun ti pèsè ọ̀gbun tí ó ṣókùnkùn biribiri fún wọn. Ọ̀rọ̀ kàǹkà-kàǹkà lásán, tí kò ní ìtumọ̀, ní ń ti ẹnu wọn jáde. Nípa ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara ati ìwà ìbàjẹ́ wọn, wọ́n ń tan àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kúrò láàrin ìwà ìtànjẹ ti ẹgbẹ́ wọ́n àtijọ́ jẹ. Wọ́n ṣèlérí òmìnira fún àwọn eniyan, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹrú ohun ìbàjẹ́ wọn ni àwọn fúnra wọn jẹ́, nítorí tí ohunkohun bá ti borí eniyan, olúwarẹ̀ di ẹrú nǹkan náà. Nítorí bí wọ́n bá ti bọ́ lọ́wọ́ ìbàjẹ́ ayé nípa mímọ Oluwa ati olùgbàlà wa, Jesu Kristi, tí wọ́n tún wá pada sí ìwà àtijọ́, tí ìwà yìí bá tún borí wọn, ìgbẹ̀yìn wọn á wá burú ju ipò tí wọ́n wà lákọ̀ọ́kọ́ lọ. Nítorí ó sàn fún wọn kí wọn má mọ ọ̀nà òdodo ju pé kí wọn wá mọ̀ ọ́n tán kí wọn wá yipada kúrò ninu òfin mímọ́ tí a ti fi kọ́ wọn. Àwọn ni òtítọ́ òwe yìí ṣẹ mọ́ lára pé, “Ajá tún pada lọ kó èébì rẹ̀ jẹ.” Ati òwe kan tí wọn máa ń pa pé, “Ẹlẹ́dẹ̀ tí wọ́n fọ̀ nù yóo tún pada lọ yíràá ninu ẹrọ̀fọ̀.” Ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, èyí ni ìwé keji tí mo kọ si yín. Ninu ìwé mejeeji, mò ń ji yín pẹ́pẹ́, láti ran yín létí àwọn ohun tí ẹ mọ̀, kí ẹ lè fi ọkàn tòótọ́ rò wọ́n jinlẹ̀. Ẹ ranti àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn wolii ti sọ ati òfin Oluwa wa ati Olùgbàlà tí ẹ gbà lọ́wọ́ aposteli yín. Ní àkọ́kọ́, kí ẹ mọ èyí pé ní ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn tí wọn óo máa fi ẹ̀sìn ṣe ẹlẹ́yà yóo wá, tí wọn óo máa ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn. Wọn óo máa sọ pé, “Kí ni ó ṣẹlẹ̀ sí ìlérí pé Jesu tún ń pada bọ̀? Nítorí láti ìgbà tí àwọn baba wa ninu igbagbọ ti lọ tán, bákan náà ni gbogbo nǹkan rí láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé!” Nítorí wọ́n fi ojú fo èyí dá pé, láti ìgbà àtijọ́ ni àwọn ọ̀run ti wà, ati pé láti inú omi ni ilẹ̀ ti jáde nípa àṣẹ Ọlọrun. Omi kan náà ni Ọlọrun fi pa ayé tí ó ti wà rí run. Ṣugbọn àṣẹ kan náà ni Ọlọrun fi pa àwọn ọ̀run ati ayé ti àkókò yìí mọ́ kí ó lè dáná sun ún, ó ń fi wọ́n pamọ́ títí di ọjọ́ ìdájọ́ nígbà tí a óo pa àwọn eniyan tí kò bẹ̀rù Ọlọrun run. Ẹ̀yin ará, ẹ má fi ojú fo èyí dá, pé níwájú Oluwa ọjọ́ kan dàbí ẹgbẹrun ọdún, ẹgbẹrun ọdún sì dàbí ọjọ́ kan. Oluwa kò jáfara nípa ìlérí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ti rò, ṣugbọn ó ń mú sùúrù fun yín ni. Kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣègbé ṣugbọn ó fi ààyè sílẹ̀ kí gbogbo eniyan lè ronupiwada. Ṣugbọn bí olè ni ọjọ́ Oluwa yóo dé. Ní ọjọ́ náà, àwọn ọ̀run yóo parẹ́ pẹlu ariwo ńlá bí ìgbà tí iná ńlá bá ń jó ìgbẹ́. Àwọn ẹ̀dá ojú ọ̀run yóo fò, wọ́n óo sì jóná. Ayé ati gbogbo nǹkan inú rẹ̀ yóo wá wà ní ìhòòhò. Nígbà tí ìparun ń bọ̀ wá bá gbogbo nǹkan báyìí, irú ìgbé-ayé wo ni ó yẹ kí ẹ máa gbé? Ẹ níláti jẹ́ eniyan ọ̀tọ̀ ati olùfọkànsìn, kí ẹ máa retí ọjọ́ Ọlọrun, kí ẹ máa ṣe akitiyan pé kí ó tètè dé. Ní ọjọ́ náà, àwọn ọ̀run yóo parun, gbogbo ẹ̀dá ojú ọ̀run yóo yọ́ ninu iná. Gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀, à ń dúró de àwọn ọ̀run titun ati ayé titun níbi tí òdodo yóo máa wà. Nítorí náà, ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, nígbà tí ẹ̀ ń retí nǹkan wọnyi, ẹ máa ní ìtara láti wà láì lábùkù ati láì lábàwọ́n, kí ẹ wà ní alaafia pẹlu Ọlọrun. Ẹ fi í sọ́kàn pé ìdí tí Oluwa wa fi mú sùúrù ni pé kí á lè ní ìgbàlà, bí Paulu arakunrin wa àyànfẹ́ ti kọ̀wé si yín, gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fi fún un. Ninu gbogbo àwọn ìwé rẹ̀, nǹkankan náà ní ó ń sọ nípa ọ̀rọ̀ wọnyi. Ninu àwọn ìwé wọnyi, àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn le. Àwọn òpè ati àwọn tí wọn kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ a máa yí ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ pada sí ìparun ara wọn, bí wọ́n ti ń yí àwọn ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́ yòókù. Nítorí náà, ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, a ti kìlọ̀ fun yín tẹ́lẹ̀. Ẹ ṣọ́ra kí àwọn eniyan burúkú wọnyi má baà tàn yín sí inú ìṣìnà wọn, kí ẹ má baà ṣubú lórí ìpìlẹ̀ tí ẹ dúró sí. Ṣugbọn ẹ máa dàgbà ninu oore-ọ̀fẹ́ ati ìmọ̀ Oluwa ati olùgbàlà wa, Jesu Kristi. Tirẹ̀ ni ògo nisinsinyii ati títí laelae. Amin. Ohun tí ó ti wà láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé, ohun tí a ti gbọ́, tíí ṣe ọ̀rọ̀ ìyè, tí a ti fi ojú ara wa rí, tí a wò dáradára, tí a fi ọwọ́ wa dìmú, òun ni à ń sọ fun yín. Ìyè yìí farahàn, a ti rí i, a sì ń jẹ́rìí rẹ̀. Ìyè ainipẹkun yìí tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Baba, tí ó ti farahàn fún wa, ni a wá ń kéde fun yín. Ohun tí a ti rí, tí a sì ti gbọ́ ni à ń kéde fun yín, kí ẹ lè ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu wa. Ìrẹ́pọ̀ yìí ni a ní pẹlu Baba ati pẹlu Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi. À ń kọ àwọn nǹkan wọnyi si yín kí ayọ̀ wa lè kún. Iṣẹ́ tí ó fi rán wa, tí à ń jẹ́ fun yín nìyí: pé ìmọ́lẹ̀ ni Ọlọrun, kò sí òkùnkùn ninu rẹ̀ rárá. Bí a bá wí pé a ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu rẹ̀, tí a bá ń gbé inú òkùnkùn, òpùrọ́ ni wá, a kò sì ṣe olóòótọ́. Ṣugbọn bí a bá ń gbé inú ìmọ́lẹ̀, bí òun náà ti wà ninu ìmọ́lẹ̀, a ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu ara wa, ẹ̀jẹ̀ Jesu Ọmọ rẹ̀ sì ti wẹ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa nù kúrò lára wa. Bí a bá wí pé a kò lẹ́ṣẹ̀, ara wa ni à ń tàn jẹ, òtítọ́ kò sì sí ninu wa. Ṣugbọn bí a bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa: olóòótọ́ ati olódodo ni òun, yóo wẹ àìṣedéédé gbogbo nù kúrò lára wa. Bí a bá wí pé àwa kò dẹ́ṣẹ̀ rí, a mú Ọlọrun lékèé, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì sí ninu wa. Ẹ̀yin ọmọ mi, mò ń kọ ìwé yìí si yín, kí ẹ má baà dẹ́ṣẹ̀. Bí ẹnikẹ́ni bá wá dẹ́ṣẹ̀, a ní alágbàwí kan pẹlu Baba tíí ṣe Jesu Kristi olódodo. Òun fúnrarẹ̀ ni ọ̀nà ìwẹ̀mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa. Kì í ṣe tiwa nìkan, ṣugbọn ti gbogbo ayé pẹlu. Ọ̀nà tí a fi lè mọ̀ pé a mọ Ọlọrun ni pé bí a bá ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́. Òpùrọ́ ni ẹni tí ó bá wí pé òun mọ̀ ọ́n, ṣugbọn tí kò bá máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́, kò sí òtítọ́ ninu olúwarẹ̀. Ó dájú pé ìfẹ́ Ọlọrun ti di pípé ninu ẹnikẹ́ni tí ó bá ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́. Ọ̀nà tí a fi mọ̀ pé a wà ninu rẹ̀ nìyí ẹni tí ó bá wí pé òun ń gbé inú Ọlọrun níláti máa gbé irú ìgbé-ayé tí Jesu fúnrarẹ̀ gbé. Olùfẹ́, kì í ṣe òfin titun ni mò ń kọ si yín. Òfin àtijọ́ tí ẹ ti níláti ìbẹ̀rẹ̀ ni. Òfin àtijọ́ náà ni ọ̀rọ̀ tí ẹ ti gbọ́. Ṣugbọn ní ìdàkejì, òfin titun ni mò ń kọ si yín, èyí tí a rí òtítọ́ rẹ̀ ninu Jesu Kristi ati ninu yín, nítorí pé òkùnkùn ń kọjá lọ, ìmọ́lẹ̀ tòótọ́ sì ti ń tàn. Ẹni tí ó bá wí pé òun wà ninu ìmọ́lẹ̀, tí ó kórìíra arakunrin rẹ̀, wà ninu òkùnkùn sibẹ. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn arakunrin rẹ̀ ń gbé inú ìmọ́lẹ̀, ohun ìkọsẹ̀ kò sí ninu olúwarẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí ó bá kórìíra arakunrin rẹ̀ wà ninu òkùnkùn; kò mọ ibi tí ó ń lọ, nítorí òkùnkùn ti fọ́ ọ lójú. Ẹ̀yin ọmọde, mò ń kọ ìwé si yín, nítorí pé a ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín nítorí orúkọ Jesu. Ẹ̀yin baba, mò ń kọ ìwé si yín, nítorí pé ẹ ti mọ ẹni tí ó wà láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé. Ẹ̀yin ọdọmọkunrin, mò ń kọ ìwé si yín, nítorí pé ẹ ti ṣẹgun Èṣù. Ẹ̀yin ọmọde, mo kọ ìwé si yín, nítorí pé ẹ ti mọ Baba. Ẹ̀yin baba, mo kọ ìwé si yín, nítorí pé ẹ ti mọ ẹni tí ó wà láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé. Ẹ̀yin ọdọmọkunrin, mo kọ ìwé si yín, nítorí pé ẹ lágbára, ọ̀rọ̀ Ọlọrun ń gbé inú yín, ẹ sì ti ṣẹgun Èṣù. Ẹ má fẹ́ràn ayé tabi àwọn nǹkan ayé. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn ayé kò ní ìfẹ́ sí Baba. Nítorí gbogbo nǹkan tí ó wà ninu ayé: ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, ìwòkúwò ojú ati afẹfẹyẹ̀yẹ̀ ayé kò wá láti ọ̀dọ̀ Baba bíkòṣe láti inú ayé. Ayé ati ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ń kọjá lọ, ṣugbọn ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọrun yóo wà títí lae. Ẹ̀yin ọmọde, àkókò ìkẹyìn nìyí! Gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gbọ́ pé Alátakò Kristi ń bọ̀, nisinsinyii ọpọlọpọ àwọn alátakò Kristi ti ń yọjú. Èyí ni a fi mọ̀ pé àkókò ìkẹyìn nìyí. Ọ̀dọ̀ wa ni wọ́n ti kúrò ṣugbọn wọn kì í ṣe ara wa. Nítorí bí ó bá jẹ́ pé ara wa ni wọ́n, wọn ìbá dúró lọ́dọ̀ wa. Ṣugbọn kí ó lè hàn dájú pé gbogbo wọn kì í ṣe ara wa ni wọ́n ṣe kúrò lọ́dọ̀ wa. Ẹ̀yin ni Ẹ̀mí Mímọ́ ti fi òróró yàn, gbogbo yín sì mọ òtítọ́. Kì í ṣe pé ẹ kò mọ òtítọ́ ni mo ṣe kọ ìwé si yín, ṣugbọn nítorí pé ẹ mọ̀ ọ́n ni, kò sí irọ́ kankan tí ó lè jáde láti inú òtítọ́. Ta ni òpùrọ́ bí ẹni tí ó bá kọ̀ láti gbà pé Jesu ni Mesaya? Olúwarẹ̀ ni Alátakò Kristi, tí ó kọ Baba ati Ọmọ. Ẹni tí ó bá kọ Ọmọ kò ní Baba. Ṣugbọn ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ Ọmọ ní Baba pẹlu. Ẹ̀yin ẹ jẹ́ kí ohun tí ẹ gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ máa gbé inú yín. Bí ohun tí ẹ gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ bá ń gbé inú yín, ẹ̀yin yóo máa gbé inú Ọmọ ati Baba. Ìlérí tí òun fúnrarẹ̀ ṣe fún wa ni ìyè ainipẹkun. Mò ń kọ nǹkan wọnyi si yín nípa àwọn kan tí wọn ń tàn yín jẹ; ẹ jẹ́ kí òróró tí Jesu ta si yín lórí máa gbé inú yín, ẹ kò sì nílò ẹnikẹ́ni láti máa kọ yín lẹ́kọ̀ọ́. Ṣugbọn gẹ́gẹ́ bí òróró rẹ̀ ninu yín ti ń kọ yín nípa ohun gbogbo, òtítọ́ ni, kì í ṣe irọ́, ẹ máa gbé inú rẹ̀, bí ó ti kọ yín. Ǹjẹ́ nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbé inú rẹ̀, kí á lè ní ìgboyà nígbà tí ó bá farahàn, kí ojú má baà tì wá láti wá siwaju rẹ̀ nígbà tí ó bá dé. Bí ẹ bá mọ̀ pé olódodo ni, ẹ mọ̀ pé gbogbo ẹni tí ó bá ń ṣe òdodo ni ọmọ rẹ̀. Ẹ wo irú ìfẹ́ tí Baba fẹ́ wa tí a fi ń pè wá ní ọmọ Ọlọrun! Bẹ́ẹ̀ gan-an ni a sì jẹ́. Nítorí náà, ayé kò mọ̀ wá, nítorí wọn kò mọ Ọlọrun. Olùfẹ́, nisinsinyii ọmọ Ọlọrun ni wá. Ohun tí a óo dà kò ì tíì hàn sí wa. A mọ̀ pé nígbà tí Jesu Kristi bá yọ, bí ó ti rí ni àwa náà yóo rí, nítorí a óo rí i gẹ́gẹ́ bí ó ti rí. Gbogbo ẹni tí ó bá ní ìrètí yìí ninu Jesu yóo wẹ ara rẹ̀ mọ́ gẹ́gẹ́ bí Jesu fúnrarẹ̀, ti jẹ́ mímọ́. Gbogbo ẹni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀ ń rú òfin, nítorí rírú òfin ni ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ sì mọ̀ pé Jesu wá láti kó ẹ̀ṣẹ̀ lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun alára kò dá ẹyọ ẹ̀ṣẹ̀ kan. Gbogbo ẹni tí ó bá ń gbé inú rẹ̀ kò ní máa dẹ́ṣẹ̀. Ẹni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀ kò ì tíì rí i, kò sì tíì mọ̀ ọ́n. Ẹ̀yin ọmọde, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe òdodo ni olódodo, bí Jesu ti jẹ́ olódodo. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń hùwà ẹ̀ṣẹ̀, láti ọ̀dọ̀ Èṣù ni ó ti wá, nítorí láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé ni Èṣù ti ń dẹ́ṣẹ̀. Nítorí èyí ni Ọmọ Ọlọrun ṣe wá, kí ó lè pa àwọn iṣẹ́ Èṣù run. Gbogbo ẹni tí a bí láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun kò ní máa dẹ́ṣẹ̀ nítorí irú-ọmọ Ọlọrun yóo máa gbé inú olúwarẹ̀, nítorí náà, kò ní máa dẹ́ṣẹ̀ nítorí a bí i láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Ọ̀nà tí a fi lè mọ àwọn ọmọ Ọlọrun yàtọ̀ sí àwọn ọmọ Èṣù nìyí: gbogbo ẹni tí kò bá ṣe iṣẹ́ òdodo tí kò sì fẹ́ràn arakunrin rẹ̀ kò wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Nítorí èyí ni iṣẹ́ tí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀, pé kí á fẹ́ràn ara wa. Kí á má dàbí Kaini tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Èṣù, tí ó pa arakunrin rẹ̀. Kí ló dé tí ó fi pa á? Nítorí iṣẹ́ tirẹ̀ burú, ṣugbọn ti arakunrin rẹ̀ dára. Ẹ má jẹ́ kí ẹnu yà yín bí ayé bá kórìíra yín. Àwa mọ̀ pé a ti rékọjá láti inú ikú sí inú ìyè, nítorí a fẹ́ràn àwọn arakunrin. Ẹni tí kò bá ní ìfẹ́ wà ninu ikú. Apànìyàn ni ẹnikẹ́ni tí ó bá kórìíra arakunrin rẹ̀. Ẹ sì ti mọ̀ pé kò sí apànìyàn kan tí ìyè ainipẹkun ń gbé inú rẹ̀. Ọ̀nà tí a fi mọ ìfẹ́ nìyí, pé ẹnìkan fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa. Nítorí náà, ó yẹ kí àwa náà fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ fún àwọn ará. Bí ẹnìkan bá ní dúkìá ayé yìí, tí ó rí arakunrin rẹ̀ tí ó ṣe aláìní, tí kò ṣàánú rẹ̀, a ṣe lè wí pé ìfẹ́ Ọlọrun ń gbé inú irú ẹni bẹ́ẹ̀? Ẹ̀yin ọmọde, ẹ má jẹ́ kí ìfẹ́ wa jẹ́ ti ọ̀rọ̀ ẹnu tabi ti ètè lásán; ṣugbọn kí ó jẹ́ ti ìwà ati ti òtítọ́. Ọ̀nà tí a óo fi mọ̀ pé a jẹ́ ẹni òtítọ́ nìyí; níwájú Ọlọrun pàápàá ọkàn wa yóo balẹ̀. Bí ọkàn wa bá tilẹ̀ dá wa lẹ́bi, kí á ranti pé Ọlọrun tóbi ju ọkàn wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo. Olùfẹ́, bí ọkàn wa kò bá dá wa lẹ́bi, a ní ìgboyà níwájú Ọlọrun. À ń rí ohunkohun tí a bá bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ gbà, nítorí pé à ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́, a sì ń ṣe ohun tí ó dára lójú rẹ̀. Àṣẹ rẹ̀ nìyí: pé kí á gba orúkọ Ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi, gbọ́, kí á sì fẹ́ràn ẹnìkejì wa, gẹ́gẹ́ bí Jesu ti fi àṣẹ fún wa. Ẹni tí ó bá ń pa òfin Ọlọrun mọ́ ń gbé inú Ọlọrun, Ọlọrun náà ń gbé inú irú ẹni bẹ́ẹ̀. Ọ̀nà tí a fi mọ̀ pé Ọlọrun ń gbé inú wa ni nípa Ẹ̀mí tí ó ti fi fún wa. Olùfẹ́, ẹ má ṣe gba gbogbo ẹni tí ó bá wí pé òun ní Ẹ̀mí Ọlọrun gbọ́. Ẹ kọ́kọ́ wádìí wọn láti mọ ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun, nítorí ọpọlọpọ àwọn èké wolii ti wọ inú ayé. Ọ̀nà tí a óo fi mọ Ẹ̀mí Ọlọrun nìyí: gbogbo ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wá sáyé gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ran-ara jẹ́ ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Gbogbo ẹni tí kò bá jẹ́wọ́ bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ti Ọlọrun. Alátakò Kristi tí ẹ ti gbọ́ pé ó ń bọ̀ ni irú ẹni bẹ́ẹ̀. Ó ti dé inú ayé nisinsinyii. Ẹ̀yin ọmọde, ti Ọlọrun nìyí, ẹ ti ṣẹgun ẹ̀mí alátakò Kristi nítorí pé ẹni tí ó wà ninu yín tóbi ju ẹni tí ó wà ninu ayé lọ. Láti inú ayé ni àwọn yìí ti wá; nítorí náà, wọ́n ń sọ nǹkan ti ayé, àwọn aráyé sì ń gbọ́ tiwọn. Ti Ọlọrun ni àwa; Ẹni tí ó bá mọ Ọlọrun ń gbọ́ tiwa; ẹni tí kì í bá ṣe ti Ọlọrun kò ní gbọ́ tiwa. Ọ̀nà tí a fi mọ Ẹ̀mí òtítọ́ ati ẹ̀mí ìtànjẹ yàtọ̀ nìyí. Olùfẹ́, ẹ jẹ́ kí á fẹ́ràn ẹnìkejì wa, nítorí ìfẹ́ ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá. Ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni a ti bí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìfẹ́, ó sì mọ Ọlọrun. Ẹni tí kò bá ní ìfẹ́ kò mọ Ọlọrun nítorí ìfẹ́ ni Ọlọrun. Ọ̀nà tí Ọlọrun fi fi ìfẹ́ tí ó ní sí wa hàn ni pé ó ti rán ààyò ọmọ rẹ̀ wá sáyé kí á lè ní ìgbàlà nípasẹ̀ rẹ̀. Ọ̀nà tí a fi mọ ìfẹ́ nìyí: kì í ṣe pé àwa ni a fẹ́ràn Ọlọrun ṣugbọn òun ni ó fẹ́ràn wa, tí ó rán ọmọ rẹ̀ wá sáyé láti jẹ́ ọ̀nà ìwẹ̀mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa. Olùfẹ́, bí Ọlọrun bá fẹ́ràn wa tó báyìí, ó yẹ kí àwa náà fẹ́ràn ọmọnikeji wa. Ẹnikẹ́ni kò rí Ọlọrun rí, bí a bá fẹ́ràn ọmọnikeji wa, Ọlọrun ń gbé inú wa, ìfẹ́ rẹ̀ sì ti di pípé ninu wa. A mọ̀ pé à ń gbé inú Ọlọrun ati pé òun náà ń gbé inú wa nítorí pé ó fún wa ní ẹ̀mí rẹ̀. Àwa ti rí i, a sì ń jẹ́rìí pé Baba ti rán Ọmọ rẹ̀ láti jẹ́ olùgbàlà aráyé. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ pé Ọmọ Ọlọrun ni Jesu, Ọlọrun ń gbé inú rẹ̀, òun náà sì ń gbé inú Ọlọrun. A mọ ìfẹ́ tí Ọlọrun ní sí wa, a sì ní igbagbọ ninu ìfẹ́ yìí. Ìfẹ́ ni Ọlọrun. Ẹni tí ó bá ń gbé inú ìfẹ́ ń gbé inú Ọlọrun, Ọlọrun náà sì ń gbé inú rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ ṣe di pípé ninu wa, kí á lè ní ìgboyà ní ọjọ́ ìdájọ́ pé bí ó ti rí ni àwa náà rí ninu ayé yìí. Kò sí ẹ̀rù ninu ìfẹ́; ìfẹ́ pípé a máa lé ẹ̀rù jáde, nítorí ìjayà ni ó ń mú ẹ̀rù wá. Ẹni tí ó bá ń bẹ̀rù kò ì tíì di pípé ninu ìfẹ́. A fẹ́ràn rẹ̀ nítorí pé Ọlọrun ni ó kọ́ fẹ́ràn wa. Bí ẹnikẹ́ni bá wí pé, òun fẹ́ràn Ọlọrun, tí ó bá kórìíra arakunrin rẹ̀, èké ni. Nítorí ẹni tí kò bá fẹ́ràn arakunrin rẹ̀ tí ó ń fojú rí, kò lè fẹ́ràn Ọlọrun tí kò rí. Àṣẹ tí a rí gbà láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi ni pé ẹni tí ó bá fẹ́ràn Ọlọrun, kí ó fẹ́ràn arakunrin rẹ̀ pẹlu. Gbogbo ẹni tí ó bá gbàgbọ́ pé Jesu ni Mesaya, a bí i láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Gbogbo ẹni tí ó bá fẹ́ràn baba yóo fẹ́ràn Ọmọ rẹ̀. Ọ̀nà tí a fi lè mọ̀ pé a fẹ́ràn àwọn ọmọ Ọlọrun ni pé kí á fẹ́ràn Ọlọrun kí á sì máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Fífẹ́ràn Ọlọrun ni pé kí á pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́: àwọn àṣẹ rẹ̀ kò sì wọni lọ́rùn, nítorí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọrun ti ṣẹgun ayé. Igbagbọ wa ni ìṣẹ́gun lórí ayé. Ta ni ó ti ṣẹgun ayé? Àfi ẹni tí ó bá gbàgbọ́ pé Ọmọ Ọlọrun ni Jesu. Òun yìí ni ó wà nípa omi ati ẹ̀jẹ̀, àní Jesu Kristi. Kì í ṣe nípa omi nìkan, ṣugbọn nípa omi ati ẹ̀jẹ̀. Ẹ̀mí ni ó ń jẹ́rìí, nítorí òtítọ́ ni Ẹ̀mí. Àwọn ẹlẹ́rìí mẹta ni ó wà: Ẹ̀mí, omi ati ẹ̀jẹ̀. Nǹkankan náà ni àwọn mẹtẹẹta ń tọ́ka sí. À ń gba ẹ̀rí eniyan, ṣugbọn ẹ̀rí Ọlọrun tóbi ju ti eniyan lọ; nítorí ẹ̀rí Ọlọrun ni, tí ó jẹ́ nípa Ọmọ rẹ̀. Ẹni tí ó bá gba Ọmọ Ọlọrun gbọ́ ní ẹ̀rí yìí ninu ara rẹ̀. Ẹni tí kò bá gba Ọlọrun gbọ́ mú Ọlọrun lékèé, nítorí kò gba ẹ̀rí tí Ọlọrun ti jẹ́ nípa Ọmọ rẹ̀ gbọ́. Ẹ̀rí náà ni pé Ọlọrun ti fún wa ní ìyè ainipẹkun, ìyè yìí sì wà ninu Ọmọ rẹ̀. Ẹni tí ó bá ní Ọmọ ní ìyè; ẹni tí kò bá ní Ọmọ Ọlọrun kò ní ìyè. Mo kọ èyí si yín, ẹ̀yin tí ẹ gba orúkọ Ọmọ Ọlọrun gbọ́, kí ẹ lè mọ̀ pé ẹ ní ìyè ainipẹkun. Ìgboyà tí a ní níwájú Ọlọrun nìyí, pé bí a bá bèèrè ohunkohun ní ọ̀nà tí ó fẹ́, yóo gbọ́ tiwa. Bí a bá sì mọ̀ pé ó ń gbọ́ tiwa nípa ohunkohun tí a bá bèèrè, a mọ̀ pé à ń rí gbogbo ohun tí a bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ gbà. Bí ẹnikẹ́ni bá rí arakunrin rẹ̀ tí ó ń dẹ́ṣẹ̀ kan, tí kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ó jẹ mọ́ ti ikú, kí ó gbadura fún un, Ọlọrun yóo fún un ní ìyè. Mò ń sọ nípa àwọn tí wọn ń dẹ́ṣẹ̀ tí kò jẹ mọ́ ti ikú. Ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn wà tí ó la ti ikú lọ. N kò wí pé kí eniyan gbadura fún irú rẹ̀. Gbogbo aiṣododo ni ẹ̀ṣẹ̀, ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn wà tí kò jẹ mọ́ ti ikú. A mọ̀ pé kò sí ọmọ Ọlọrun kan tíí máa gbé inú ẹ̀ṣẹ̀, nítorí pé Jesu Kristi Ọmọ Ọlọrun ń pa á mọ́, Èṣù kò sì ní fọwọ́ kàn án. A mọ̀ pé láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni a ti wá, ati pé gbogbo ayé patapata wà lábẹ́ Èṣù. A tún mọ̀ pé Ọmọ Ọlọrun ti dé, ó ti fún wa ní làákàyè kí á lè mọ ẹni Òtítọ́. À ń gbé inú Ọlọrun, àní inú Ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi. Òun ni Ọlọrun tòótọ́ ati ìyè ainipẹkun. Ẹ̀yin ọmọde, ẹ má bá wọn bọ oriṣa. Èmi Alàgbà ni mo kọ ìwé yìí sí àyànfẹ́ arabinrin ati àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn tí mo fẹ́ràn nítòótọ́. Kì í ṣe èmi nìkan ni mo fẹ́ràn rẹ̀, ati gbogbo àwọn tí wọ́n mọ òtítọ́ ni; nítorí òtítọ́ tí ó ń gbé inú wa, tí ó sì wà pẹlu wa yóo wà títí lae. Oore-ọ̀fẹ́, àánú ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba ati láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi Ọmọ Baba yóo wà pẹlu wa ninu òtítọ́ ati ìfẹ́. Mo láyọ̀ pupọ nítorí mo ti rí àwọn tí wọn ń gbé ìgbé-ayé òtítọ́ ninu àwọn ọmọ rẹ, gẹ́gẹ́ bí a ti gba òfin lọ́dọ̀ Baba. Nisinsinyii mo bẹ̀ ọ́, arabinrin, kì í ṣe pé mò ń kọ òfin titun sí ọ, yàtọ̀ sí èyí tí a ti níláti ìbẹ̀rẹ̀, pé kí á fẹ́ràn ọmọnikeji wa. Èyí ni ìfẹ́, pé kí á máa gbé ìgbé-ayé gẹ́gẹ́ bí àwọn òfin Ọlọrun. Bí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀, òfin yìí ni pé kí ẹ máa rìn ninu ìfẹ́. Ọpọlọpọ àwọn ẹlẹ́tàn ti dé inú ayé, àwọn tí kò jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wá ninu ara eniyan. Àwọn yìí ni ẹlẹ́tàn ati alátakò Kristi. Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà pa iṣẹ́ tí ẹ ti ṣe run, kí ẹ lè gba èrè kíkún. Ẹnikẹ́ni tí kò bá máa gbé inú ẹ̀kọ́ Kristi, ṣugbọn tí ó bá tayọ rẹ̀, kò mọ Ọlọrun. Ẹni tí ó bá ń gbé inú ẹ̀kọ́ Kristi mọ Baba ati Ọmọ. Bí ẹnikẹ́ni bá wá sọ́dọ̀ yín tí kò mú ẹ̀kọ́ yìí wá, ẹ má gbà á sílé. Ẹ má tilẹ̀ kí i, “Kú ààbọ̀.” Ẹni tí ó bá kí i di alábàápín ninu àwọn iṣẹ́ burúkú rẹ̀. Àwọn nǹkan tí mo fẹ́ ba yín sọ pọ̀, ṣugbọn n kò fẹ́ kọ ọ́ sinu ìwé. Mo ní ìrètí ati wá sọ́dọ̀ yín, kí á baà lè jọ sọ̀rọ̀ lojukooju, kí ayọ̀ wa lè di kíkún. Àwọn ọmọ àyànfẹ́ arabinrin rẹ kí ọ. Èmi, Alàgbà, ni mo kọ ìwé yìí sí ọ, Gaiyu olùfẹ́, ẹni tí mo fẹ́ràn nítòótọ́. Olùfẹ́, mo gbadura pé kí ó dára fún ọ ní gbogbo ọ̀nà ati pé kí o ní ìlera, gẹ́gẹ́ bí o ti ní ìlera ninu ẹ̀mí. Inú mi dùn nígbà tí àwọn arakunrin dé, tí wọ́n ròyìn rẹ pé o ṣe olóòótọ́ sí ọ̀nà òtítọ́, ati pé ò ń gbé ìgbé-ayé òtítọ́. Ayọ̀ mi kì í lópin, nígbà tí mo bá gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń gbé ìgbé-ayé òtítọ́. Olùfẹ́, ohun rere ni ò ń ṣe fún àwọn arakunrin, bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ àlejò. Níwájú gbogbo ìjọ níhìn-ín wọ́n jẹ́rìí sí oríṣìíríṣìí ọ̀nà tí ó fi ràn wọ́n lọ́wọ́ ninu ìrìn àjò wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ fún òṣìṣẹ́ Ọlọrun. Nítorí pé orúkọ Jesu ni ó mú wọn máa rin ìrìn àjò láì gba ohunkohun lọ́wọ́ àwọn alaigbagbọ. Ó yẹ kí á máa ran irú wọn lọ́wọ́ kí á lè jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹlu wọn ninu iṣẹ́ òtítọ́. Mo kọ ìwé kan sí ìjọ ṣugbọn Diotirefe tí ó fẹ́ ipò aṣiwaju láàrin ìjọ kò gba ohun tí mo sọ. Nítorí náà, nígbà tí mo bá dé, n óo ranti àwọn iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ń ṣe, tí ó ń sọ ìsọkúsọ nípa mi. Kò fi ọ̀ràn mọ bẹ́ẹ̀; kò gba àwọn arakunrin tí wọ́n wá, àwọn tí wọ́n sì fẹ́ gbà wọ́n, kò jẹ́ kí wọ́n gbà wọ́n, ó tún fẹ́ yọ wọ́n kúrò ninu ìjọ! Olùfẹ́, má tẹ̀lé àpẹẹrẹ burúkú, ṣugbọn tẹ̀lé àpẹẹrẹ rere. Ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni ẹni tí ó bá ń ṣe rere ti wá. Ẹni tí ó bá ń ṣe burúkú kò mọ Ọlọrun. Gbogbo eniyan ni wọ́n ń ròyìn Demeteriu ní rere. Òtítọ́ pàápàá ń jẹ́rìí rẹ̀. Èmi náà jẹ́rìí sí i, o sì mọ̀ pé òtítọ́ ni ẹ̀rí mi. Mo ní ohun pupọ tí mo fẹ́ bá ọ sọ, ṣugbọn n kò fẹ́ kọ ọ́ sinu ìwé. Mo ní ìrètí ati rí ọ láìpẹ́, nígbà náà a óo lè jọ sọ̀rọ̀ lojukooju. Kí alaafia máa bá ọ gbé. Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ wa níhìn-ín kí ọ. Bá wa kí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ wa lọ́kọ̀ọ̀kan. Èmi Juda, iranṣẹ Jesu Kristi, tí mo jẹ́ arakunrin Jakọbu ni mò ń kọ ìwé yìí sí àwọn tí Ọlọrun Baba fẹ́ràn, tí Jesu Kristi pè láti pamọ́. Kí àánú, alaafia ati ìfẹ́ kí ó máa pọ̀ sí i fun yín. Ẹ̀yin olùfẹ́, mo ti gbìyànjú títí láti kọ ìwé si yín nípa ìgbàlà tí a jọ ní, nígbà tí mo rí i pé ó di dandan pé kí n kọ ìwé si yín, kí n rọ̀ yín pé kí ẹ máa jà fún igbagbọ tí Ọlọrun fi fún àwọn eniyan rẹ̀ mímọ́ lẹ́ẹ̀kan gbọ̀n-ọ́n. Nítorí àwọn kan ti yọ́ wọ inú ìjọ, àwọn tí Ìwé Mímọ́ ti sọ nípa wọn lọ́jọ́ tó ti pẹ́ pé ìdájọ́ ń bọ̀ sórí wọn. Wọ́n jẹ́ aláìbọ̀wọ̀ fún Ọlọrun, wọ́n yí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun wa pada sí àìdára láti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ inú wọn, wọ́n sẹ́ Ọ̀gá wa kanṣoṣo ati Oluwa wa Jesu Kristi. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ti mọ gbogbo nǹkan wọnyi, sibẹ mo fẹ́ ran yín létí pé lẹ́yìn tí Oluwa ti gba àwọn eniyan là kúrò ní ilẹ̀ Ijipti tán, nígbà tí ó yá, ó tún pa àwọn tí kò gbàgbọ́ run. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn angẹli tí wọn kọjá ààyè wọn àkọ́kọ́, tí wọ́n kúrò ní ipò tí Ọlọrun kọ́ fi wọ́n sí. Ẹ̀wọ̀n ayérayé ni Ọlọrun fi dè wọ́n mọ́ inú òkùnkùn biribiri títí di ọjọ́ ńlá nnì tíí ṣe ọjọ́ ìdájọ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni ìlú Sodomu ati ìlú Gomora ati àwọn ìlú tí ó yí wọn ká. Àwọn náà ṣe bí àwọn angẹli tí wọ́n kọjá ààyè wọn, wọ́n ṣe àgbèrè ati oríṣìíríṣìí ohun ìbàjẹ́ tí kò bá ìwà eniyan mu. Ọlọrun fi wọ́n ṣe àpẹẹrẹ fún gbogbo eniyan nígbà tí wọ́n jìyà iná ajónirun. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó rí fún àwọn eniyan wọnyi lónìí. Àlá tí wọn ń lá, fún ìbàjẹ́ ara wọn ni. Wọ́n tàpá sí àwọn aláṣẹ. Wọ́n ń sọ ìsọkúsọ sí àwọn ẹ̀dá ọ̀run tí ó lógo. Nígbà tí Mikaeli, olórí àwọn angẹli pàápàá ń bá Èṣù jiyàn, tí wọ́n ń jìjàdù òkú Mose, kò tó sọ ìsọkúsọ sí i. Ohun tí ó sọ ni pé, “Oluwa yóo bá ọ wí.” Ṣugbọn àwọn eniyan wọnyi a máa sọ ìsọkúsọ nípa ohunkohun tí kò bá ti yé wọn. Àwọn nǹkan tí ó bá sì yé wọn, bí nǹkan tíí yé ẹranko ni. Ohun tí ń mú ìparun bá wọn nìyí. Ó ṣe fún wọn! Wọ́n ń rìn ní ọ̀nà Kaini. Wọ́n tẹra mọ́ ọ̀nà ẹ̀tàn Balaamu nítorí ohun tí wọn yóo rí gbà. Wọ́n dá ọ̀tẹ̀ sílẹ̀ bíi Kora, wọ́n sì parun. Bàsèjẹ́ ni wọ́n jẹ́ ninu àsè ìfẹ́ ìjọ, wọn kò ní ọ̀wọ̀ nígbà tí ẹ bá jọ ń jẹ, tí ẹ jọ ń mu. Ara wọn nìkan ni wọ́n ń tọ́jú bí olùṣọ́-aguntan tí ń tọ́jú ara rẹ̀ dípò aguntan. Wọ́n dàbí ìkùukùu tí afẹ́fẹ́ ń gbá kiri tí kò rọ òjò. Igi tí kò ní èso ní àkókò ìkórè ni wọ́n, wọ́n ti kú sára. Nígbà tí ó bá ṣe, wọn á wó lulẹ̀ tigbòǹgbò-tigbòǹgbò. Ìgbì omi òkun líle ni wọ́n, tí ó ń rú ìwà ìtìjú wọn jáde. Ìràwọ̀ tí kò gbébìkan ni wọ́n. Ààyè wọn ti wà nílẹ̀ fún wọn, ninu òkùnkùn biribiri títí ayé ainipẹkun. Nípa àwọn wọnyi ni Enọku tí ó jẹ́ ìran keje sí Adamu sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé, “Mo rí Oluwa tí ó dé pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun lọ́nà ẹgbẹrun àwọn angẹli rẹ̀ mímọ́, láti ṣe ìdájọ́ lórí gbogbo ẹ̀dá. Yóo bá gbogbo àwọn eniyan burúkú wí fún gbogbo ìwà burúkú tí wọ́n ti hù, ati gbogbo ọ̀rọ̀ líle tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò bẹ̀rù Ọlọrun ti sọ sí òun Oluwa.” Àwọn wọnyi ni àwọn tí wọn ń kùn ṣá, nǹkan kì í fi ìgbà kan tẹ́ wọn lọ́rùn. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn ni wọ́n ń lépa. Ẹnu wọn gba ọ̀rọ̀ kàǹkà-kàǹkà. Kò sí ohun tí wọn kò lè ṣe láti rí ohun tí wọ́n fẹ́. Wọn á máa wá ojú rere àwọn tí wọ́n bá lè rí nǹkan gbà lọ́wọ́ wọn. Ṣugbọn ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, ẹ̀yin ẹ ranti ohun tí Oluwa wa Jesu Kristi ti ti ẹnu àwọn aposteli rẹ̀ sọ tẹ́lẹ̀. Wọ́n kìlọ̀ fun yín pé ní àkókò ìkẹyìn, àwọn kan yóo máa fi ẹ̀sìn ṣe ẹlẹ́yà, wọn yóo máa tẹ̀lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn láì bẹ̀rù Ọlọrun. Àwọn wọnyi ni wọ́n ń ya ara wọn sọ́tọ̀. Wọ́n hùwà bí ẹranko, wọn kò ní Ẹ̀mí Mímọ́. Ṣugbọn ẹ̀yin, àyànfẹ́ mi, ẹ fi igbagbọ yín tí ó mọ́ jùlọ ṣe odi fún ara yín, kí ẹ máa gbadura nípa agbára tí ó wà ninu Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ pa ara yín mọ́ ninu ìfẹ́ Ọlọrun. Ẹ máa retí ìyè ainipẹkun tí Oluwa wa Jesu Kristi yóo fun yín ninu àánú rẹ̀. Ẹ máa ṣàánú àwọn tí ó ń ṣiyèméjì. Inú iná ni ẹ ti níláti yọ àwọn mìíràn kí ẹ tó lè gbà wọ́n là. Ìbẹ̀rù-bojo ni kí ẹ fi máa ṣàánú àwọn mìíràn. Ẹ níláti kórìíra aṣọ tí ìfẹ́ ara ti da àbààwọ́n sí. Ǹjẹ́ fún ẹni tí ó lè pa yín mọ́ tí ẹ kò fi ní ṣubú, tí ó lè mu yín dúró pẹlu ayọ̀ níwájú ògo rẹ̀ láì lábàwọ́n, Ọlọrun nìkan ṣoṣo, Olùgbàlà wa nípasẹ̀ Jesu Kristi Oluwa wa ni ògo, ọlá, agbára ati àṣẹ wà fún, kí á tó dá ayé, ati nisinsinyii ati títí ayé ainipẹkun. Amin. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó níláti ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ nìyí, tí Ọlọrun fún Jesu Kristi, pé kí ó fihan àwọn iranṣẹ rẹ̀. Jesu wá rán angẹli rẹ̀ sí Johanu, iranṣẹ rẹ̀, pé kí ó fi àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà hàn án. Johanu sọ gbogbo nǹkan tí ó rí nípa ọ̀rọ̀ Ọlọrun ati ẹ̀rí Jesu Kristi. Ẹni tí ó bá ń ka ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí ati àwọn tí ó bá ń gbọ́, tí wọ́n sì ń ṣe àwọn ohun tí a kọ, ṣe oríire. Nítorí àkókò tí yóo ṣẹlẹ̀ súnmọ́ tòsí. Èmi Johanu ni mo ranṣẹ sí ìjọ meje tí ó wà ní agbègbè Esia. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia wà pẹlu yín láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ti wà, tí ó ń bẹ, tí ó sì tún ń bọ̀ wá, ati láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí meje tí wọ́n wà níwájú ìtẹ́ rẹ̀; ati láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, ẹlẹ́rìí òtítọ́, ẹnikinni tí ó jinde láti inú òkú ati aláṣẹ lórí àwọn ọba ilé ayé. Ẹni tí ó fẹ́ràn wa, tí ó fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ó sọ wá di ìjọba, ati alufaa Ọlọrun Baba rẹ̀. Tirẹ̀ ni ògo ati agbára lae ati laelae. Amin. Wò ó! Ó ń bọ̀ ninu awọsanma, gbogbo eniyan ni yóo sì rí i. Àwọn tí wọ́n gún un lọ́kọ̀ náà yóo rí i. Gbogbo ẹ̀yà ilẹ̀ ayé yóo dárò nígbà tí wọ́n bá rí i. Amin! Àṣẹ! “Èmi ni Alfa ati Omega, ìbẹ̀rẹ̀ ati òpin.” Oluwa Ọlọrun ló sọ bẹ́ẹ̀, ẹni tí ó ti wà, tí ń bẹ, tí ó sì tún ń bọ̀ wá, Olodumare. Èmi ni Johanu, arakunrin yín ati alábàápín pẹlu yín ninu ìpọ́njú tí ẹni tí ó bá tẹ̀lé Jesu níláti rí, ati ìfaradà tí ó níláti ní. Wọ́n jù mí sí ilẹ̀ kan tí ń jẹ́ Patimosi nítorí mo waasu ọ̀rọ̀ Ọlọrun, mo sì jẹ́rìí pé Jesu ni mo gbàgbọ́. Erékùṣù ni ilẹ̀ Patimosi, ó wà láàrin omi. Nígbà tí ó di Ọjọ́ Oluwa, ni Ẹ̀mí bá gbé mi. Mo gbọ́ ohùn ńlá kan lẹ́yìn mi bí ìgbà tí fèrè bá ń dún, ó ní, “Kọ ohun tí o bá rí sinu ìwé, kí o fi ranṣẹ sí àwọn ìjọ ní ìlú mejeeje wọnyi: Efesu ati Simana, Pẹgamu ati Tiatira, Sadi ati Filadẹfia ati Laodikia.” Mo bá yipada láti wo ẹni tí ń bá mi sọ̀rọ̀. Bí mo ti yipada, mo rí ọ̀pá fìtílà wúrà meje. Ní ààrin àwọn ọ̀pá fìtílà yìí ni ẹnìkan wà tí ó dàbí eniyan. Ó wọ ẹ̀wù tí ó balẹ̀ dé ilẹ̀. Ó fi ọ̀já wúrà gba àyà. Irun orí rẹ̀ funfun gbòò bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Ojú rẹ̀ ń kọ yànràn bí iná. Ẹsẹ̀ rẹ̀ dàbí idẹ tí ń dán, tí alágbẹ̀dẹ ń dà ninu iná. Ohùn rẹ̀ dàbí híhó omi òkun. Ó mú ìràwọ̀ meje lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀. Idà olójú meji tí ó mú yọ jáde lẹ́nu rẹ̀. Ojú rẹ̀ mọ́lẹ̀ bí oòrùn ọ̀sán gangan. Nígbà tí mo rí i, mo ṣubú lulẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀ bí ẹni tí ó kú. Ó bá gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé mi. Ó ní, “Má bẹ̀rù. Èmi ni ẹni kinni ati ẹni ìkẹyìn. Èmi ni ẹni tí ó wà láàyè. Mo kú, ṣugbọn mo ti jí, mo sì wà láàyè lae ati laelae. Àwọn kọ́kọ́rọ́ ikú ati ti ipò òkú wà lọ́wọ́ mi. Nítorí náà kọ àwọn ohun tí o rí sílẹ̀, ati àwọn ohun tí ó wà nisinsinyii ati àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la. Àṣírí ìràwọ̀ meje tí o rí ní ọwọ́ ọ̀tún mi, ati ti ọ̀pá fìtílà wúrà meje nìyí: ìràwọ̀ meje ni àwọn angẹli ìjọ meje. Ọ̀pá fìtílà meje ni àwọn ìjọ meje. “Kọ ìwé yìí sí òjíṣẹ́ ìjọ Efesu: “Ẹni tí ó di ìràwọ̀ meje mú ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, tí ó ń rìn láàrin àwọn ọ̀pá fìtílà wúrà meje wí báyìí pé, Mo mọ iṣẹ́ rẹ, ati làálàá rẹ, ati ìfaradà rẹ. Mo mọ̀ pé o kò jẹ́ gba àwọn eniyan burúkú mọ́ra. O ti dán àwọn tí wọn ń pe ara wọn ní aposteli, tí wọn kì í ṣe aposteli wò, o ti rí i pé òpùrọ́ ni wọ́n. O ní ìfaradà. O ti farada ìyà nítorí orúkọ mi, o kò sì jẹ́ kí àárẹ̀ mú ọ. Ṣugbọn mo ní nǹkan wí sí ọ. O ti kọ ìfẹ́ tí o ní nígbà tí o kọ́kọ́ gbàgbọ́ sílẹ̀. Nítorí náà, ranti bí o ti ga tó tẹ́lẹ̀ kí o tó ṣubú; ronupiwada, kí o sì ṣiṣẹ́ bíi ti àkọ́kọ́. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, mò ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, bí o kò bá ronupiwada, n óo mú ọ̀pá fìtílà rẹ kúrò ní ipò rẹ̀. Ṣugbọn ò ń ṣe kinní kan tí ó dára: o kórìíra iṣẹ́ àwọn Nikolaiti, tí èmi náà kórìíra. “Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. “Ẹni tí ó bá ṣẹgun ni n óo fún ní àṣẹ láti jẹ ninu èso igi ìyè tí ó wà ninu ọgbà Ọlọrun. “Kọ ìwé yìí sí angẹli ìjọ Simana: “Báyìí ni ẹni kinni ati ẹni ìkẹyìn wí, ẹni tí ó kú, tí ó tún wà láàyè: Mo mọ̀ pé o ní ìṣòro; ati pé o ṣe aláìní, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ́rọ̀ ni ọ́ ní ọ̀nà mìíràn. Mo mọ ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ tí àwọn tí wọn ń pe ara wọn ní Juu ń sọ, àwọn tí kì í sì í ṣe Juu; tí ó jẹ́ pé ilé ìpàdé Satani ni wọ́n. Má bẹ̀rù ohunkohun tí ò ń bọ̀ wá jìyà. Èṣù yóo gbé ẹlòmíràn ninu yín jù sinu ẹ̀wọ̀n láti fi dán yín wò. Fún ọjọ́ mẹ́wàá ẹ óo ní ìṣòro pupọ. Ṣugbọn jẹ́ olóòótọ́ dé ojú ikú, Èmi yóo sì fún ọ ní adé ìyè. “Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. “Ẹni tí ó bá ṣẹgun kò ní kú ikú keji. “Kọ ìwé yìí sí angẹli ìjọ Pẹgamu pé: “Ẹni tí ó ní idà olójú meji tí ó mú ní: Mo mọ ibi tí ò ń gbé, ibẹ̀ ni Satani tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí. Sibẹ o di orúkọ mi mú, o kò bọ́hùn ninu igbagbọ ní ọjọ́ tí wọ́n pa Antipasi ẹlẹ́rìí òtítọ́ mi ní ìlú yín níbi tí Satani fi ṣe ilé. Ṣugbọn mo ní àwọn nǹkan díẹ̀ wí sí ọ. O ní àwọn kan láàrin ìjọ tí wọ́n gba ẹ̀kọ́ Balaamu, ẹni tí ó kọ́ Balaki láti fi ohun ìkọsẹ̀ siwaju àwọn ọmọ Israẹli, tí wọ́n fi ń jẹ oúnjẹ ìbọ̀rìṣà, tí wọ́n tún ń ṣe àgbèrè. O tún ní àwọn kan tí àwọn náà gba ẹ̀kọ́ àwọn Nikolaiti. Nítorí náà, ronupiwada. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ n óo wá láìpẹ́, n óo sì fi idà tí ó wà lẹ́nu mi bá wọn jà. “Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. “Ẹni tí ó bá ṣẹgun, Èmi óo fún un ní mana tí a ti fi pamọ́. N óo tún fún un ní òkúta funfun kan tí a ti kọ orúkọ titun sí lára. Ẹnikẹ́ni kò mọ orúkọ titun yìí àfi ẹni tí ó bá gba òkúta náà. “Kọ ìwé yìí sí ìjọ Tiatira pé: “Ọmọ Ọlọrun, ẹni tí ojú rẹ̀ dàbí ọwọ́ iná, tí ẹsẹ̀ rẹ̀ ń dán bí idẹ. Mo mọ iṣẹ́ rẹ. Mo mọ ìfẹ́ rẹ ati igbagbọ rẹ, mo mọ iṣẹ́ rere tí ò ń ṣe ati ìfaradà rẹ. Iṣẹ́ rẹ ti ìkẹyìn tilẹ̀ dára ju ti àkọ́kọ́ lọ. Ṣugbọn mo ní nǹkan wí sí ọ. O gba obinrin tí wọn ń pè ní Jesebẹli láàyè. Ó ń pe ara rẹ̀ ní aríran, ó ń tan àwọn iranṣẹ mi jẹ, ó ń kọ́ wọn láti ṣe àgbèrè ati láti jẹ oúnjẹ ìbọ̀rìṣà. Mo fún un ní àkókò kí ó ronupiwada, ṣugbọn kò fẹ́ ronupiwada kúrò ninu ìwà àgbèrè rẹ̀. N óo dá a dùbúlẹ̀ àìsàn. Ìṣòro pupọ ni yóo bá àwọn tí wọ́n bá bá a ṣe àgbèrè, àfi bí wọ́n bá rí i pé iṣẹ́ burúkú ni ó ń ṣe, tí wọn kò sì bá a lọ́wọ́ ninu rẹ̀ mọ́. N óo fi ikú pa àwọn ọmọ rẹ̀. Gbogbo àwọn ìjọ ni yóo wá mọ̀ pé Èmi ni Èmi máa ń wádìí ọkàn ati èrò ẹ̀dá, n óo sì fi èrè fún olukuluku yín gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀. “Ṣugbọn ẹ̀yin yòókù ní Tiatira, ẹ̀yin tí ẹ kò gba ẹ̀kọ́ obinrin yìí, ẹ̀yin tí ẹ kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí wọn ń pè ní ohun ìjìnlẹ̀ Satani, n kò ní di ẹrù mìíràn rù yín mọ́. Ṣugbọn ṣá, ẹ di ohun tí ẹ ní mú ṣinṣin títí n óo fi dé. Ẹni tí ó bá ṣẹgun, tí ó forí tì í, tí ó ń ṣe iṣẹ́ mi títí dé òpin, òun ni n óo fún ní àṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè, ọ̀pá irin ni yóo fi jọba lórí wọn, bí ìkòkò amọ̀ ni yóo fọ́ wọn túútúú. Irú àṣẹ tí mo gbà lọ́dọ̀ Baba mi ni n óo fún un. N óo tún fún un ní ìràwọ̀ òwúrọ̀. *** *** “Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. “Kọ ìwé yìí sí angẹli ìjọ Sadi: “Ẹni tí ó ní Ẹ̀mí Ọlọrun meje ati ìràwọ̀ meje ní: Mo mọ iṣẹ́ rẹ. O kàn ní orúkọ pé o wà láàyè ni, òkú ni ọ́! Jí lójú oorun! Fún àwọn ohun tí ó ṣẹ́kù ní okun, nítorí àwọn náà ń kú lọ. Nítorí n kò rí iṣẹ́ kan tí o ṣe parí níwájú Ọlọrun mi. Nítorí náà, ranti ohun tí o ti gbà tí o sì ti gbọ́, ṣe é, kí o sì ronupiwada. Bí o kò bá jí lójú oorun, n óo dé bí olè, o kò sì ní mọ àkókò tí n óo dé bá ọ. Ṣugbọn o ní àwọn díẹ̀ ninu ìjọ Sadi tí wọn kò fi èérí ba aṣọ wọn jẹ́. Wọn yóo bá mi kẹ́gbẹ́ ninu aṣọ funfun nítorí wọ́n yẹ. Ẹni tí ó bá ṣẹgun ni a óo wọ̀ ní aṣọ funfun bẹ́ẹ̀. N kò ní pa orúkọ rẹ̀ rẹ́ kúrò ninu ìwé ìyè. N óo jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀ níwájú Baba mi ati níwájú àwọn angẹli rẹ̀. “Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. “Kọ ìwé yìí sí angẹli ìjọ Filadẹfia pé: “Ẹni mímọ́ ati olóòótọ́ nì, ẹni tí kọ́kọ́rọ́ Dafidi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, tíí ṣí ìlẹ̀kùn tí ẹnikẹ́ni kò lè tì í, tíí sìí tìlẹ̀kùn tí ẹnikẹ́ni kò lè ṣí i, ó ní: Mo mọ iṣẹ́ rẹ. Wò ó! Mo fi ìlẹ̀kùn kan tí ó ṣí sílẹ̀ siwaju rẹ, tí ẹnikẹ́ni kò lè tì. Mo mọ̀ pé agbára rẹ kéré, sibẹ o ti pa ọ̀rọ̀ mi mọ́. O kò sẹ́ orúkọ mi. N óo fi àwọn kan láti inú ilé ìpàdé Satani lé ọ lọ́wọ́, àwọn òpùrọ́ tí wọn ń pe ara wọn ní Juu, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kì í ṣe Juu. N óo ṣe é tí wọn yóo fi wá sọ́dọ̀ rẹ, wọn yóo foríbalẹ̀ fún ọ, wọn yóo sì mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ. Nítorí o ti fi ìfaradà pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, Èmi náà yóo pa ọ́ mọ́ ní àkókò ìdánwò tí ń bọ̀ wá bá ayé, nígbà tí a óo dán gbogbo àwọn tí ó ń gbé inú ayé wò. Mò ń bọ̀ kíákíá. Di ohun tí ń bẹ lọ́wọ́ rẹ mú ṣinṣin, kí ẹnikẹ́ni má baà gba adé rẹ. Ẹni tí ó bá ṣẹgun ni n óo fi ṣe òpó ninu Tẹmpili Ọlọrun mi. Kò ní kúrò níbẹ̀ mọ́. N óo wá kọ orúkọ Ọlọrun mi ati orúkọ mi titun sí i lára, ati ti Jerusalẹmu titun, ìlú Ọlọrun mi, tí ń sọ̀kalẹ̀ bọ̀ láti ọ̀run, láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun mi. “Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń bá àwọn ìjọ sọ. “Kọ ìwé yìí sí angẹli ìjọ Laodikia pé: “Ẹni tí ń jẹ́ Amin, olóòótọ́ ati ẹlẹ́rìí òdodo, alákòóso ẹ̀dá Ọlọrun ní Mo mọ iṣẹ́ rẹ. Mo mọ̀ pé o kò gbóná, bẹ́ẹ̀ ni o kò tutù. Ninu kí o gbóná tabi kí o tutù, ó yẹ kí o ṣe ọ̀kan. Nítorí pé o lọ́ wọ́ọ́rọ́wọ́ lásán, o kò gbóná, bẹ́ẹ̀ ni o kò tutù, n óo pọ̀ ọ́ jáde lẹ́nu mi. Nítorí ò ń sọ pé: Mo lówó, mo lọ́rọ̀. Kò sí ohun tí mo fẹ́ tí n kò ní. O kò mọ̀ pé akúṣẹ̀ẹ́ tí eniyan ń káàánú ni ọ́, òtòṣì afọ́jú tí ó wà ní ìhòòhò. Mo dá ọ nímọ̀ràn pé kí o ra wúrà tí wọ́n ti dà ninu iná lọ́wọ́ mi, kí o lè ní ọrọ̀, kí o ra aṣọ funfun kí o fi bora, kí ìtìjú ìhòòhò tí o wà má baà hàn, sì tún ra òògùn ojú, kí o fi sí ojú rẹ kí o lè ríran. Àwọn tí mo bá fẹ́ràn ni mò ń bá wí, àwọn ni mò ń tọ́ sọ́nà. Nítorí náà ní ìtara, kí o sì ronupiwada. Wò ó! Mo dúró ní ẹnu ọ̀nà, mò ń kan ìlẹ̀kùn. Bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ohùn mi, tí ó ṣílẹ̀kùn, n óo wọlé tọ̀ ọ́ lọ, n óo bá a jẹun, òun náà yóo sì bá mi jẹun. Ẹni tí ó bá ṣẹgun ni n óo jẹ́ kí ó jókòó tì mí lórí ìtẹ́ mi, gẹ́gẹ́ bí Èmi náà ti ṣẹgun, tí mo jókòó ti baba mi lórí ìtẹ́ rẹ̀. “Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń bá àwọn ìjọ sọ.” Lẹ́yìn èyí mo tún rí ìran mìíran. Mo rí ìlẹ̀kùn kan tí ó ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run. Mo wá gbọ́ ohùn kan bíi ti àkọ́kọ́. Tí ó dàbí ìgbà tí kàkàkí bá ń dún, tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀. Ó ní, “Gòkè wá níhìn-ín. N óo fi àwọn ohun tí ó níláti ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn èyí hàn ọ́.” Lẹsẹkẹsẹ ni Ẹ̀mí bá gbé mi. Mo bá rí ìtẹ́ kan ní ọ̀run. Ẹnìkan jókòó lórí rẹ̀. Ojú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà dàbí òkúta iyebíye oríṣìí meji. Òṣùmàrè yí ìtẹ́ náà ká, ó ń tan ìmọ́lẹ̀ bí òkúta iyebíye. Àwọn ìtẹ́ mẹrinlelogun ni wọ́n yí ìtẹ́ náà ká. Àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun sì jókòó lórí ìtẹ́ mẹrinlelogun náà. Wọ́n wọ aṣọ funfun, wọ́n dé adé wúrà. Mànàmáná ati ìró ààrá ń jáde láti ara ìtẹ́ tí ó wà láàrin. Ògùṣọ̀ meje tí iná wọn ń jó wà níwájú ìtẹ́ náà. Àwọn yìí ni Ẹ̀mí Ọlọrun meje. Iwájú ìtẹ́ náà dàbí òkun dígí, ó rí bíi yìnyín, ó mọ́ gaara. Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin kan wà ní ààrin, wọ́n yí ìtẹ́ náà ká. Wọ́n ní ọpọlọpọ ojú níwájú ati lẹ́yìn. Ekinni dàbí kinniun, ekeji dàbí akọ mààlúù, ojú ẹkẹta jọ ti eniyan, ẹkẹrin sì dàbí idì tí ó ń fò. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà ní apá mẹfa. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ọpọlọpọ ojú. Wọn kì í sinmi tọ̀sán-tòru, wọ́n ń wí pé, “Mímọ́! Mímọ́! Mímọ́! Oluwa Ọlọrun Olodumare. Ẹni tí ó ti wà, tí ó wà nisinsinyii, tí ó sì ń bọ̀ wá.” Nígbà tí àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà bá fi ògo, ọlá ati ìyìn fún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, ẹni tí ó wà láàyè lae ati laelae, àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun náà á dojúbolẹ̀ níwájú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, wọn a júbà ẹni tí ó wà láàyè lae ati laelae, wọn a fi adé wọn lélẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wọ́n a máa wí pé, “Oluwa Ọlọrun wa, ìwọ ni ó tọ́ sí láti gba ògo, ati ọlá ati agbára. Nítorí ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, ati pé nípa ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, nípa rẹ ni a sì ṣe dá wọn.” Lẹ́yìn náà, mo rí ìwé kan ní ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́: wọ́n kọ nǹkan sí i ninu ati lóde, wọ́n sì fi èdìdì meje dì í. Mo sì rí angẹli alágbára kan tí ń ké pẹlu ohùn rara pé, “Ta ni ó yẹ láti ṣí ìwé náà, ati láti tú èdìdì rẹ̀?” Kò sí ẹnikẹ́ni ní ọ̀run, tabi lórí ilẹ̀ tabi nísàlẹ̀ ilẹ̀ tí ó lè ṣí ìwé náà tabi tí ó lè wò ó. Mo sunkún lọpọlọpọ nítorí kò sí ẹnikẹ́ni tí ó yẹ láti ṣí ìwé náà ati láti wò ó. Ọ̀kan ninu àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun yìí wá sọ fún mi pé, “Má sunkún mọ́! Wò ó! Kinniun ẹ̀yà Juda, ọmọ Dafidi, ti borí. Ó le ṣí ìwé náà ó sì le tú èdìdì meje tí a fi dì í.” Mo bá rí Ọ̀dọ́ Aguntan tí ó dúró láàrin ìtẹ́ náà, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin ati àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun náà yí i ká. Ọ̀dọ́ Aguntan náà dàbí ẹni pé wọ́n ti pa á. Ìwo meje ni ó ní ati ojú meje. Àwọn ojú meje yìí ni Ẹ̀mí Ọlọrun meje tí Ọlọrun rán sí gbogbo orílẹ̀ ayé. Ọ̀dọ́ Aguntan náà bá wá, ó sì gba ìwé náà ní ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́. Nígbà tí ó gbà á, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin ati àwọn mẹrinlelogun náà dojúbolẹ̀ níwájú Ọ̀dọ́ Aguntan yìí. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn mú hapu kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́, ati àwo wúrà kéékèèké, tí ó kún fún turari. Turari yìí ni adura àwọn eniyan Ọlọrun, àwọn onigbagbọ. Wọ́n wá ń kọ orin titun kan, pé, “Ìwọ ni ó tọ́ sí láti gba ìwé náà, ati láti tú èdìdì ara rẹ̀. Nítorí wọ́n pa ọ́, o sì ti fi ẹ̀jẹ̀ rẹ bá Ọlọrun ṣe ìràpadà eniyan, láti inú gbogbo ẹ̀yà, ati gbogbo eniyan ní gbogbo orílẹ̀-èdè. O ti sọ wọ́n di ìjọba ti alufaa láti máa sin Ọlọrun wa. Wọn yóo máa jọba ní ayé.” Bí mo tí ń wò, mo gbọ́ ohùn ọpọlọpọ àwọn angẹli tí wọ́n yí ìtẹ́ náà ká ati àwọn ẹ̀dá alààyè ati àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun. Àwọn angẹli náà pọ̀ pupọ: ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀nà ẹgbẹẹgbẹrun àìmọye. Wọ́n ń kígbe pé, “Ọ̀dọ́ Aguntan tí a ti pa ni ó tọ́ sí láti gba agbára, ọrọ̀, ọgbọ́n, ipá, ọlá, ògo ati ìyìn.” Mo bá tún gbọ́ tí gbogbo ẹ̀dá tí ó wà lọ́run ati ní orílẹ̀ ayé, ati nísàlẹ̀ ilẹ̀, ati lórí òkun, ati ohun gbogbo tí ń bẹ ninu òkun, ń wí pé, “Ìyìn, ọlá, ògo, ati agbára ni ti ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ ati Ọ̀dọ́ Aguntan lae ati laelae.” Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà bá dáhùn pé, “Amin!” Àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun sì dojúbolẹ̀, wọ́n júbà Ọlọrun. Mo rí Ọ̀dọ́ Aguntan náà nígbà tí ó ń tú ọ̀kan ninu àwọn èdìdì meje náà. Mo gbọ́ tí ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin wí pẹlu ohùn tí ó dàbí ààrá, pé, “Wá!” Mo bá rí ẹṣin funfun kan. Ẹni tí ó gùn ún mú ọrun ati ọfà lọ́wọ́. A fún un ní adé kan, ó bá jáde lọ bí aṣẹ́gun, ó ń ṣẹgun bí ó ti ń lọ. Nígbà tí ó tú èdìdì keji, mo gbọ́ tí ẹ̀dá alààyè keji ní, “Wá!” Ni ẹṣin mìíràn bá yọ jáde, òun pupa. A fi agbára fún ẹni tí ó gùn ún láti mú alaafia kúrò ní ayé, kí àwọn eniyan máa pa ara wọn. A wá fún un ní idà kan tí ó tóbi. Nígbà tí ó tú èdìdì kẹta, mo gbọ́ tí ẹ̀dá alààyè kẹta ní, “Wá!” Mo rí ẹṣin dúdú kan. Ẹni tí ó gùn ún mú ìwọ̀n kan lọ́wọ́. Mo wá gbọ́ nǹkankan tí ó dàbí ohùn láàrin àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà, ó ní, “Páànù ọkà bàbà kan fún owó fadaka kan. Páànù ọkà baali mẹta fún owó fadaka kan. Ṣugbọn o kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan igi olifi ati ọtí waini.” Nígbà tí ó tú èdìdì kẹrin, mo gbọ́ tí ẹ̀dá alààyè kẹrin ní, “Wá!” Mo wá rí ẹṣin kan tí àwọ̀ rẹ̀ rí bíi ti ewéko tútù. Orúkọ ẹni tí ó gùn ún ni Ikú. Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni Ipò-òkú. A fún wọn ní àṣẹ láti fi idà ati ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn ati ẹranko burúkú pa idamẹrin ayé. Nígbà tí ó tú èdìdì karun-un, ní abẹ́ pẹpẹ ìrúbọ, mo rí ọkàn àwọn tí a ti pa nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọrun ati nítorí ẹ̀rí tí wọ́n jẹ́. Àwọn náà kígbe pé, “Oluwa mímọ́ ati olóòótọ́, nígbà wo ni ìwọ yóo ṣe ìdájọ́ fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé, tí ìwọ yóo gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ wa lára wọn?” A wá fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní aṣọ funfun. A sọ fún wọn pé kí wọ́n sinmi díẹ̀ sí i títí iye àwọn iranṣẹ ẹlẹgbẹ́ wọn ati àwọn arakunrin wọn yóo fi pé, àwọn tí wọn yóo pa láìpẹ́ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti pa àwọn ti iṣaaju. Mo rí i nígbà tí ó tú èdìdì kẹfa pé ilẹ̀ mì tìtì. Oòrùn ṣókùnkùn, ó dàbí aṣọ dúdú. Òṣùpá wá dàbí ẹ̀jẹ̀. Àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run já bọ́ sílẹ̀, bí ìgbà tí èso ọ̀pọ̀tọ́ bá já bọ́ lára igi rẹ̀ nígbà tí afẹ́fẹ́ líle bá fẹ́ lù ú. Ojú ọ̀run fẹ́ lọ bí ìgbà tí eniyan bá ká ẹní. Gbogbo òkè ati erékùṣù ni wọ́n kúrò ní ipò wọn. Àwọn ọba ayé, àwọn ọlọ́lá, àwọn ọ̀gágun, àwọn olówó, àwọn alágbára, ati gbogbo eniyan: ẹrú ati òmìnira, gbogbo wọn lọ sápamọ́ sinu ihò òkúta ati abẹ́ àpáta lára àwọn òkè. Wọ́n ń sọ fún àwọn òkè ati àpáta pé, “Ẹ wó lù wá, kí ẹ pa wá mọ́ kúrò lójú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ ati ibinu Ọ̀dọ́ Aguntan. Nítorí ọjọ́ ńlá ibinu wọn dé; kò sì sí ẹni tí ó lè dúró.” Lẹ́yìn èyí, mo rí àwọn angẹli mẹrin tí wọ́n dúró ní igun mẹrẹẹrin ayé, tí wọ́n di afẹ́fẹ́ mẹrẹẹrin ayé mú kí afẹ́fẹ́ má baà fẹ́ lórí ilẹ̀ ayé ati lórí òkun ati lára gbogbo igi. Mo bá tún rí angẹli mìíràn tí ó gòkè wá láti ìhà ìlà oòrùn, tí ó mú èdìdì Ọlọrun alààyè lọ́wọ́. Ó kígbe lóhùn rara sí àwọn angẹli mẹrẹẹrin tí a fún ní agbára láti ṣe ayé ní jamba. Ó ní, “Ẹ má ì tíì ṣe ilẹ̀ ayé ati òkun ati àwọn igi ní jamba títí tí a óo fi fi èdìdì sí àwọn iranṣẹ Ọlọrun wa níwájú.” Mo gbọ́ iye àwọn tí a fi èdìdì sí níwájú, wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ meje eniyan ó lé ẹgbaaji (144,000) láti inú gbogbo ẹ̀yà ọmọ Israẹli: Láti inú ẹ̀yà Juda ẹgbaafa (12,000) ni a fi èdìdì sí níwájú, láti inú ẹ̀yà Reubẹni, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Gadi, ẹgbaafa (12,000); láti inú ẹ̀yà Aṣeri, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Nafutali, ẹgbaafa (12,000) láti inú ẹ̀yà Manase, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Simeoni, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Lefi, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Isakari, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Sebuluni ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Josẹfu, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, ẹgbaafa (12,000). *** *** *** Lẹ́yìn náà, mo rí ọ̀pọ̀ eniyan tí ẹnikẹ́ni kò lè kà láti gbogbo orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà, ati oríṣìíríṣìí èdè, wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ náà ati níwájú Ọ̀dọ́ Aguntan. Wọ́n wọ aṣọ funfun. Wọ́n mú imọ̀ ọ̀pẹ lọ́wọ́. Wọ́n wá ń kígbe pé, “Ti Ọlọrun wa tí ó jókòó lórí ìtẹ́, ati ti Ọ̀dọ́ Aguntan ni ìgbàlà.” Gbogbo àwọn angẹli tí ó dúró yí ìtẹ́ náà ká, ati àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun ati àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin dojúbolẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wọ́n júbà Ọlọrun. Wọ́n ń wí pé, “Amin! Ìyìn, ògo, ọgbọ́n, ọpẹ́, ọlá, agbára ati ipá ni fún Ọlọrun wa lae ati laelae. Amin!” Ọ̀kan ninu àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun yìí bi mí pé, “Ta ni àwọn wọnyi tí a wọ̀ ní aṣọ funfun? Níbo ni wọ́n sì ti wá?” Mo bá dá a lóhùn pé, “Alàgbà, ìwọ ni ó mọ̀ wọ́n.” Ó wá sọ fún mi pé, “Àwọn wọnyi ni wọ́n ti kọjá ninu ọpọlọpọ ìpọ́njú. Wọ́n ti fọ aṣọ wọn, wọ́n ti sọ wọ́n di funfun ninu ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Aguntan. Nítorí èyí ni wọ́n ṣe wà níwájú ìtẹ́ Ọlọrun, tí wọn ń júbà tọ̀sán-tòru ninu Tẹmpili rẹ̀. Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà yóo máa bá wọn gbé. Ebi kò ní pa wọ́n mọ́, bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ kò ní gbẹ wọ́n mọ́. Oòrùn kò ní pa wọ́n mọ́, ooru kankan kò sì ní mú wọn mọ́. Nítorí Ọ̀dọ́ Aguntan tí ó wà láàrin ìtẹ́ náà ni yóo máa ṣe olùtọ́jú wọn, yóo máa dà wọ́n lọ síbi ìsun omi ìyè. Ọlọrun yóo wá nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn.” Nígbà tí Ọ̀dọ́ Aguntan náà tú èdìdì keje, gbogbo ohun tí ó wà ní ọ̀run parọ́rọ́ fún bí ìdajì wakati kan. Mo bá rí àwọn angẹli meje tí wọn máa ń dúró níwájú Ọlọrun, a fún wọn ní kàkàkí meje. Angẹli mìíràn tún dé, ó dúró lẹ́bàá pẹpẹ ìrúbọ. Ó mú àwo turari tí wọ́n fi wúrà ṣe lọ́wọ́. A fún un ní turari pupọ kí ó fi rúbọ pẹlu adura gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun lórí pẹpẹ ìrúbọ wúrà tí ó wà níwájú ìtẹ́ náà. Èéfín turari ati adura àwọn eniyan Ọlọrun gòkè lọ siwaju Ọlọrun láti ọwọ́ angẹli náà. Angẹli náà bá mú àwo turari yìí, ó bu iná láti orí pẹpẹ ìrúbọ kún inú rẹ̀, ó bá jù ú sí orí ilẹ̀ ayé. Ààrá bá bẹ̀rẹ̀ sí sán, mànàmáná ń kọ, ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mì tìtì. Àwọn angẹli meje tí wọ́n mú kàkàkí meje lọ́wọ́ bá múra láti fun kàkàkí wọn. Ekinni fun kàkàkí rẹ̀. Ni yìnyín ati iná pẹlu ẹ̀jẹ̀ bá tú dà sórí ilẹ̀ ayé. Ìdámẹ́ta ayé bá jóná, ati ìdámẹ́ta àwọn igi ati gbogbo koríko tútù. Angẹli keji fun kàkàkí rẹ̀. Ni a bá ju nǹkankan tí ó dàbí òkè gíga tí ó ń jóná sinu òkun. Ó bá sọ ìdámẹ́ta òkun di ẹ̀jẹ̀. Ìdámẹ́ta gbogbo ohun ẹlẹ́mìí tí ó wà ninu òkun ni wọ́n kú. Ìdámẹ́ta àwọn ọkọ̀ ojú òkun ni wọ́n sì fọ́ túútúú. Angẹli kẹta fun kàkàkí rẹ̀. Ìràwọ̀ ńlá kan bá já bọ́ láti ọ̀run. Ó bẹ̀rẹ̀ sí jóná bí ògùṣọ̀. Ó bá já sinu ìdámẹ́ta àwọn odò ati ìsun omi. Orúkọ ìràwọ̀ náà ni “Igi-kíkorò.” Ó mú kí ìdámẹ́ta omi korò, ọ̀pọ̀ eniyan ni ó sì kú nítorí oró tí ó wà ninu omi. Angẹli kẹrin fun kàkàkí rẹ̀, ìdámẹ́ta oòrùn kò bá lè ràn mọ́; ati ìdámẹ́ta òṣùpá, ati ìdámẹ́ta àwọn ìràwọ̀. Ìdámẹ́ta wọn ṣókùnkùn, kò bá sí ìmọ́lẹ̀ fún ìdámẹ́ta ọ̀sán ati ìdámẹ́ta òru. Mo tún rí ìran yìí. Mo gbọ́ tí idì kan tí ń fò ní agbede meji ọ̀run ń kígbe pé, “Ó ṣe! Ó ṣe! Ó ṣe fún gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé orí ilẹ̀ ayé nígbà tí kàkàkí tí àwọn angẹli mẹta yòókù fẹ́ fun bá dún!” Angẹli karun-un wá fun kàkàkí rẹ̀, mo bá rí ìràwọ̀ kan tí ó ti ojú ọ̀run já bọ́ sí orí ilẹ̀ ayé. A fún ìràwọ̀ yìí ní kọ́kọ́rọ́ kànga tí ó jìn tóbẹ́ẹ̀ tí eniyan kò lè dé ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ó ṣí kànga náà, èéfín bá yọ láti inú kànga yìí, ó dàbí èéfín iná ìléru ńlá. Oòrùn ati ojú ọ̀run bá ṣókùnkùn nítorí èéfín tí ó jáde láti inú kànga náà. Àwọn eṣú ti tú jáde láti inú èéfín náà, wọ́n lọ sí orí ilẹ̀ ayé. A fún wọn ní agbára bíi ti àkeekèé ayé. A sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe ohunkohun sí koríko orí ilẹ̀ tabi sí ewébẹ̀ tabi sí igi kan. Gbogbo àwọn eniyan tí kò bá ní èdìdì Ọlọrun ní iwájú wọn nìkan ni kí wọ́n ṣe léṣe. A kò gbà pé kí wọ́n pa wọ́n, oró ni kí wọ́n dá wọn fún oṣù marun-un, kí wọ́n dá wọn lóró bí ìgbà tí àkeekèé bá ta eniyan. Ní ọjọ́ náà àwọn eniyan yóo máa wá ikú ṣugbọn wọn kò ní kú; wọn yóo tọrọ ikú, ṣugbọn kò ní súnmọ́ wọn. Àwọn eṣú wọnyi dàbí àwọn ẹṣin tí a dì ní gàárì láti lọ sójú ogun. Adé wà ní orí wọn tí ó dàbí adé wúrà. Ojú wọn dàbí ojú eniyan. Irun wọn dàbí irun obinrin. Eyín wọn dàbí ti kinniun. Wọ́n ní ìgbàyà tí ó dàbí ìgbàyà irin. Ìró ìyẹ́ wọn dàbí ìró ọpọlọpọ ọkọ̀ ẹlẹ́ṣin tí wọn ń sáré lọ sójú ogun. Wọ́n ní ìrù bíi ti àkeekèé tí wọ́n fi lè ta eniyan. A fún wọn ní agbára ninu ìrù wọn láti ṣe eniyan léṣe fún oṣù marun-un. Ọba wọn ni angẹli kànga tí ó jìn tóbẹ́ẹ̀ tí eniyan kò lè dé ìsàlẹ̀ rẹ̀. Orúkọ rẹ̀ ní èdè Heberu ni Abadoni; ní èdè Giriki orúkọ rẹ̀ ni Apolioni. Ìtumọ̀ rẹ̀ ni apanirun. Ìṣòro kinni kọjá; ṣugbọn ó tún ku meji lẹ́yìn èyí. Angẹli kẹfa fun kàkàkí rẹ̀. Mo bá gbọ́ ohùn kan láti ara àwọn ìwo tí ó wà lára pẹpẹ ìrúbọ wúrà tí ó wà níwájú Ọlọrun. Ó sọ fún angẹli kẹfa tí ó mú kàkàkí lọ́wọ́ pé, “Dá àwọn angẹli mẹrin tí a ti dè ní odò ńlá Yufurate sílẹ̀.” Ni wọ́n bá dá àwọn angẹli mẹrin náà sílẹ̀. A ti pèsè wọn sílẹ̀ fún wakati yìí, ní ọjọ́ yìí, ninu oṣù yìí, ní ọdún yìí pé kí wọ́n pa ìdámẹ́ta gbogbo eniyan. Iye àwọn ọmọ-ogun ẹlẹ́ṣin jẹ́ ẹgbẹẹgbẹrun lọ́nà ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000,000). Mo gbọ́ iye wọn. Bí àwọn ẹṣin ọ̀hún ati àwọn tí ó gùn wọ́n ti rí lójú mi, lójú ìran nìyí: wọ́n gba ọ̀já ìgbàyà tí ó pọ́n bí iná, ó dàbí àyìnrín, ó tún rí bí imí-ọjọ́. Orí àwọn ẹṣin náà dàbí orí kinniun. Wọ́n ń yọ iná, ati èéfín ati imí-ọjọ́ lẹ́nu. Ohun ijamba mẹta yìí tí ó ń yọ jáde lẹ́nu wọn pa ìdá mẹta àwọn eniyan. Agbára àwọn ẹṣin wọnyi wà ní ẹnu wọn ati ní ìrù wọn. Nítorí ìrù wọn dàbí ejò, wọ́n ní orí. Òun sì ni wọ́n fi ń ṣe àwọn eniyan léṣe. Àwọn eniyan tí ó kù, tí wọn kò kú ninu àjàkálẹ̀ àrùn yìí kò ronupiwada. Wọn kò kọ iṣẹ́ ọwọ́ wọn tí wọn ń bọ sílẹ̀. Ṣugbọn wọ́n tún ń sin àwọn ẹ̀mí burúkú, ati oriṣa wúrà, ti fadaka, ti idẹ, ti òkúta, ati ti igi. Àwọn oriṣa tí kò lè ríran, wọn kò lè gbọ́ràn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè rìn. Àwọn eniyan náà kò ronupiwada kúrò ninu ìwà ìpànìyàn, ìwà oṣó, ìwà àgbèrè ati ìwà olè wọn. Mo tún rí angẹli alágbára mìíràn, tí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá. Ó fi ìkùukùu bora, òṣùmàrè sì yí orí rẹ̀ ká; ojú rẹ̀ dàbí oòrùn; ẹsẹ̀ rẹ̀ dàbí òpó iná. Ó mú ìwé kékeré kan lọ́wọ́ tí ó wà ní ṣíṣí. Ó gbé ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀ lé orí òkun, ó sì gbé ti òsì lé orí ilẹ̀ ayé. Ó wá bú ramúramù bíi kinniun. Nígbà tí ó bú báyìí tán, ààrá meje sán. Nígbà tí ààrá meje yìí ń sán, mo fẹ́ máa kọ ohun tí wọn ń sọ sílẹ̀, ṣugbọn mo gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run, tí ó sọ pé, “Àṣírí ni ohun tí àwọn ààrá meje yìí ń sọ, má kọ wọ́n sílẹ̀.” Angẹli náà tí mo rí, tí ó gbé ẹsẹ̀ lé orí òkun, ati orí ilẹ̀, wá gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ sí òkè ọ̀run, ó fi ẹni tí ó wà láàyè lae ati títí laelae búra, ẹni tí ó dá ọ̀run ati ohun tí ó wà ninu rẹ̀, tí ó dá ayé ati ohun tí ó wà ninu rẹ̀, tí ó dá òkun ati ohun tí ó wà ninu rẹ̀. Ó ní kò sí ìjáfara mọ́. Ní ọjọ́ tí angẹli keje bá fọhùn, nígbà tí ó bá fẹ́ fun kàkàkí tirẹ̀, àṣírí ète Ọlọrun yóo ṣẹlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀. Mo tún gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run tí ó sọ fún mi pé, “Lọ gba ìwé tí ó wà ni ṣíṣí tí ó wà lọ́wọ́ angẹli tí ó dúró lórí òkun ati lórí ilẹ̀.” Mo bá lọ sọ́dọ̀ angẹli náà, mo ní kí ó fún mi ní ìwé kékeré náà. Ó ní, “Gbà, kí o jẹ ẹ́. Yóo dùn ní ẹnu rẹ bí oyin, ṣugbọn yóo korò ní ikùn rẹ.” Mo bá gba ìwé náà ní ọwọ́ angẹli yìí, mo bá jẹ ẹ́. Ó dùn bí oyin ní ẹnu mi. Ṣugbọn nígbà tí mo gbé e mì, ó korò ní ikùn mi. Wọ́n bá sọ fún mi pé, “O níláti tún kéde fún ọ̀pọ̀ àwọn eniyan ati oríṣìíríṣìí ẹ̀yà ati àwọn orílẹ̀-èdè, ati ọpọlọpọ ìjọba.” Wọ́n fún mi ní ọ̀pá kan, bí èyí tí wọ́n fi ń wọn aṣọ. Wọ́n sọ fún mi pé, “Dìde! Lọ wọn Tẹmpili Ọlọrun ati pẹpẹ ìrúbọ, kí o ka iye àwọn tí wọ́n n jọ́sìn níbẹ̀. Má wulẹ̀ wọn àgbàlá Tẹmpili tí ó wà lóde, nítorí a ti fi fún àwọn alaigbagbọ. Wọn yóo gba ìlú mímọ́ fún oṣù mejilelogoji. N óo fún àwọn ẹlẹ́rìí mi meji láṣẹ láti kéde iṣẹ́ mi fún ọtalelẹgbẹfa (1260) ọjọ́. Aṣọ ọ̀fọ̀ ni wọn yóo wọ̀ ní gbogbo àkókò náà.” Àwọn wọnyi ni igi olifi meji ati ọ̀pá fìtílà meji tí ó dúró níwájú Oluwa ayé. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ pa wọ́n lára, iná ni yóo yọ lẹ́nu wọn, yóo sì jó àwọn ọ̀tá wọn run. Irú ikú bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ ṣe wọ́n ní ibi yóo kú. Wọ́n ní àṣẹ láti ti ojú ọ̀run pa, tí òjò kò fi ní rọ̀ ní gbogbo àkókò tí wọn bá ń kéde. Wọ́n tún ní àṣẹ láti sọ gbogbo omi di ẹ̀jẹ̀. Wọ́n sì lè mú kí àjàkálẹ̀ àrùn oríṣìíríṣìí bá ayé, bí wọ́n bá fẹ́. Nígbà tí wọ́n bá parí ẹ̀rí tí wọn níí jẹ́, ẹranko tí ó jáde láti inú kànga tí ó jìn tóbẹ́ẹ̀ tí eniyan kò lè dé ìsàlẹ̀ rẹ̀, yóo wá bá wọn jagun. Yóo ṣẹgun wọn, yóo sì pa wọ́n. Òkú wọn yóo wà ní títì ìlú ńlá tí a ti kan Oluwa wọn mọ́ agbelebu. Àfiwé orúkọ rẹ̀ ni Sodomu ati Ijipti. Àwọn eniyan láti inú gbogbo ẹ̀yà, ati gbogbo orílẹ̀-èdè yóo máa wo òkú wọn fún ọjọ́ mẹta ati ààbọ̀. Wọn kò ní jẹ́ kí wọ́n sin wọ́n. Àwọn ọmọ aráyé yóo máa yọ̀ wọ́n, inú wọn yóo sì máa dùn. Wọn yóo máa fún ara wọn lẹ́bùn. Nítorí pé ìyọlẹ́nu ni àwọn akéde meji wọnyi jẹ́ fún àwọn tí wọn ń gbé orí ilẹ̀ ayé. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹta ati ààbọ̀ yìí, èémí ìyè láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wọ inú wọn, ni wọ́n bá jí, wọn bá dìde dúró. Ẹ̀rù ba àwọn tí ó rí wọn gan-an. Wọ́n wá gbọ́ ohùn líle láti ọ̀run wá tí ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gòkè wá síhìn-ín.” Ni wọ́n bá gòkè lọ sọ́run ninu ìkùukùu, lójú àwọn ọ̀tá wọn. Ilẹ̀ mì tìtì, ìdámẹ́wàá ìlú bá wó. Ẹẹdẹgbaarin (7,000) eniyan ni ó kú nígbà tí ilẹ̀ náà mì. Ẹ̀rù ba àwọn tí ó kù, wọ́n sì fi ògo fún Ọlọrun ọ̀run. Ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú keji kọjá. Ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kẹta fẹ́rẹ̀ dé. Angẹli keje fun kàkàkí rẹ̀, àwọn ohùn líle kan ní ọ̀run bá sọ pé, “Ìjọba ayé di ti Oluwa wa, ati ti Kristi rẹ̀. Yóo jọba lae ati laelae.” Àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun tí wọ́n jókòó lórí ìtẹ́ wọn níwájú Ọlọrun bá dojúbolẹ̀, wọ́n júbà Ọlọrun. Wọ́n ní, “A fi ìyìn fún ọ, Oluwa, Ọlọrun Olodumare, ẹni tí ó wà, tí ó ti wà, nítorí o ti gba agbára ńlá rẹ, o sì ń jọba. Inú àwọn orílẹ̀-èdè ru, ṣugbọn àkókò ibinu rẹ dé, ó tó àkókò láti ṣe ìdájọ́ àwọn òkú, ati láti fi èrè fún àwọn iranṣẹ rẹ, àwọn wolii, àwọn eniyan rẹ, ati àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ, ìbáà ṣe àwọn mẹ̀kúnnù tabi àwọn eniyan ńláńlá. Àkókò dé láti pa àwọn tí ó ń ba ayé jẹ́ run.” Tẹmpili Ọlọrun ti ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run, tí a fi lè rí àpótí majẹmu ninu rẹ̀. Mànàmáná wá bẹ̀rẹ̀ sí kọ, ààrá ń sán, ilẹ̀ ń mì tìtì; yìnyín sì bẹ̀rẹ̀ sí bọ́ sílẹ̀. Mo wá rí àmì ńlá kan ní ọ̀run. Obinrin kan tí ó fi oòrùn ṣe aṣọ, tí òṣùpá wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó dé adé tí ó ní ìràwọ̀ mejila. Obinrin náà lóyún. Ó wá ń rọbí. Ó ń jẹ̀rora bí ó ti fẹ́ bímọ. Mo wá tún rí àmì mìíràn ní ọ̀run: Ẹranko Ewèlè ńlá kan tí ó pupa bí iná, tí ó ní orí meje ati ìwo mẹ́wàá, ó dé adé meje. Ó fi ìrù gbá ìdámẹ́ta àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run, wọ́n bá jábọ́ sórí ilẹ̀ ayé. Ẹranko Ewèlè yìí dúró níwájú obinrin tí ó fẹ́ bímọ yìí, ó fẹ́ gbé ọmọ náà jẹ bí ó bá ti bí i tán. Obinrin yìí bí ọmọkunrin, tí yóo jọba lórí àwọn orílẹ̀-èdè pẹlu ọ̀pá irin. A bá já ọmọ náà gbà lọ sọ́dọ̀ Ọlọrun, níwájú ìtẹ́ rẹ̀. Obinrin yìí bá sálọ sí aṣálẹ̀, níbìkan tí Ọlọrun ti pèsè sílẹ̀. Níbẹ̀ ni ó wà lábẹ́ ìtọ́jú fún ẹgbẹfa ọjọ́ ó lé ọgọta (1260). Ogun wá bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run. Mikaeli ati àwọn angẹli rẹ̀ ń bá Ẹranko Ewèlè náà jà. Ẹranko Ewèlè yìí ati àwọn angẹli rẹ̀ náà jà títí, ṣugbọn kò lágbára tó láti ṣẹgun. Wọ́n bá lé òun ati àwọn angẹli rẹ̀ kúrò ní ọ̀run. Wọ́n lé Ẹranko Ewèlè náà jáde–ejò àtijọ́ nì tí à ń pè ní Èṣù, tabi Satani tí ó ń tan àwọn tí ó ń gbé inú ayé jẹ. Wọ́n lé e jáde lọ sinu ayé, ati òun ati àwọn angẹli rẹ̀. Mo wá gbọ́ ohùn líle kan ní ọ̀run tí ó sọ pé, “Àkókò ìgbàlà nìyí ati ti agbára, ati ìjọba ti Ọlọrun wa, ati àkókò àṣẹ Kristi rẹ̀. Nítorí a ti lé Olùfisùn àwọn onigbagbọ ara wa jáde, tí ó ń fi ẹjọ́ wọn sùn níwájú Ọlọrun wa tọ̀sán-tòru. Wọ́n ti fi ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Aguntan ati ẹ̀rí ọ̀rọ̀ tí wọ́n jẹ́ ṣẹgun rẹ̀. Nítorí wọn kò ka ẹ̀mí wọn sí pé ó ṣe iyebíye jù kí wọ́n kú lọ. Nítorí náà, ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ọ̀run ati ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé inú wọn. Ó ṣe fun yín, ayé, ati fún òkun! Nítorí Èṣù ti dé sáàrin yín. Inú rẹ̀ ń ru, nítorí ó mọ̀ pé ìgbà díẹ̀ ni ó kù fún òun.” Nígbà tí Ẹranko Ewèlè náà rí i pé a lé òun jáde sinu ayé, ó bẹ̀rẹ̀ sí lé obinrin tí ó bí ọmọkunrin nnì kiri. Ni a bá fún obinrin náà ní ìyẹ́ idì ńláńlá meji, kí ó lè fò lọ sí aṣálẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń tọ́jú rẹ̀ fún ọdún mẹta ati oṣù mẹfa, tí ó fi bọ́ lọ́wọ́ ejò náà. Ni ejò yìí bá tú omi jáde lẹ́nu bí odò, kí omi lè gbé obinrin náà lọ. Ṣugbọn ilẹ̀ ran obinrin náà lọ́wọ́. Ilẹ̀ lanu, ó fa omi tí Ẹranko Ewèlè náà tu jáde lẹ́nu mu. Inú wá bí Ẹranko Ewèlè yìí sí obinrin náà. Ó wá lọ gbógun ti àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù, tí wọn ń pa àṣẹ Ọlọrun mọ́, tí wọn ń jẹ́rìí igbagbọ ninu Jesu. Ó dúró lórí iyanrìn etí òkun. Mo wá rí ẹranko kan tí ń ti inú òkun jáde bọ̀. Ó ní ìwo mẹ́wàá ati orí meje. Adé mẹ́wàá wà lórí ìwo rẹ̀. Ó kọ orúkọ àfojúdi sára orí rẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Ẹranko náà tí mo rí dàbí àmọ̀tẹ́kùn. Ẹsẹ̀ rẹ̀ dàbí ti ìkookò. Ẹnu rẹ̀ dàbí ti kinniun. Ẹranko Ewèlè náà fún un ní agbára rẹ̀, ati ìtẹ́ rẹ̀ ati àṣẹ ńlá rẹ̀. Ó dàbí ẹni pé wọ́n ti ṣá ọ̀kan ninu àwọn orí ẹranko náà lọ́gbẹ́. Ọgbẹ́ ọ̀hún tó ohun tí ó yẹ kí ó pa á ṣugbọn ó ti jinná. Gbogbo eniyan ni wọ́n ń tẹ̀lé ẹranko yìí tí wọ́n fi ń ṣe ìran wò. Wọ́n ń júbà Ẹranko Ewèlè náà nítorí pé ó fi àṣẹ fún ẹranko yìí. Wọ́n sì ń júbà ẹranko náà, wọ́n ń sọ pé, “Ta ni ó dàbí ẹranko yìí? Ta ni ó tó bá a jà?” A fún un ní ẹnu láti fi sọ̀rọ̀ tí ó ju ẹnu rẹ̀ lọ, ọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun. A fún un ní àṣẹ fún oṣù mejilelogoji. Ó bá ya ẹnu, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun. Ó ń sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí orúkọ Ọlọrun ati sí àgọ́ rẹ̀, ati sí àwọn tí wọ́n ń gbé ọ̀run. A fún un ní agbára láti gbógun ti àwọn eniyan Ọlọrun ati láti ṣẹgun wọn. A tún fún un ní àṣẹ lórí gbogbo ẹ̀yà ati orílẹ̀-èdè ati oríṣìíríṣìí èdè ati gbogbo eniyan. Gbogbo àwọn tí wọn ń gbé inú ayé tí a kò kọ orúkọ wọn sinu ìwé ìyè bá ń júbà rẹ̀. Láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé ni a kò ti kọ orúkọ wọn sinu ìwé Ọ̀dọ́ Aguntan tí a pa. Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́! Bí ẹnikẹ́ni bá níláti lọ sí ìgbèkùn, yóo lọ sí ìgbèkùn. Bí ẹnikẹ́ni bá fi idà pa eniyan, idà ni a óo fi pa òun náà. Níhìn-ín ni ìfaradà ati ìdúró ṣinṣin àwọn eniyan Ọlọrun yóo ti hàn. Mo tún rí ẹranko mìíràn tí ó jáde láti inú ilẹ̀. Ó ní ìwo meji bíi ti Ọ̀dọ́ Aguntan. Ó ń sọ̀rọ̀ bíi ti Ẹranko Ewèlè. Ó ń lo àṣẹ bíi ti ẹranko àkọ́kọ́, lójú ẹranko àkọ́kọ́ fúnrarẹ̀. Ó mú kí ayé ati àwọn tí ó ń gbé inú rẹ̀ júbà ẹranko àkọ́kọ́, tí ọgbẹ́ rẹ̀ ti san. Ó ń ṣe iṣẹ́ abàmì ńláńlá. Ó mú kí iná sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá sí ayé lójú àwọn eniyan. Ó fi iṣẹ́ abàmì tí a fi fún un láti ṣe níwájú ẹranko náà tan àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé jẹ. Ó sọ fún wọn pé kí wọ́n yá ère ẹranko tí a ti fi idà ṣá lọ́gbẹ́ tí ó tún yè. A fún un ní agbára láti fi èémí sinu ère ẹranko náà, kí ère ẹranko náà lè fọhùn, kí ó lè pa àwọn tí kò bá júbà ère ẹranko náà. Lẹ́yìn náà, gbogbo eniyan, ati àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan ńláńlá ati ọlọ́rọ̀ ati talaka, ati ẹrú ati òmìnira ni ẹranko yìí mú kí wọ́n ṣe àmì sí ọwọ́ ọ̀tún tabi iwájú wọn. Kò sí ẹni tí ó lè ra ohunkohun tabi kí ó ta ohunkohun àfi ẹni tí ó bá ní àmì orúkọ ẹranko náà tabi ti iye orúkọ rẹ̀ lára. Ohun tí ó gba ọgbọ́n nìyí. Ẹni tí ó bá ní òye ni ó lè mọ ìtumọ̀ àmì orúkọ ẹranko náà, nítorí pé bí orúkọ eniyan kan gan-an ni àmì yìí rí. Ìtumọ̀ iye àmì náà ni ọtalelẹgbẹta, ó lé mẹfa (666). Mo rí Ọ̀dọ́ Aguntan náà tí ó dúró lórí òkè Sioni, pẹlu àwọn ọ̀kẹ́ meje ó lé ẹgbaaji (144,000) eniyan tí a kọ orúkọ rẹ̀ ati orúkọ Baba rẹ̀ sí wọn níwájú. Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run bí ìró ọpọlọpọ omi ati bí ìgbà tí ààrá líle bá ń sán. Ohùn tí mo gbọ́ ni ti àwọn oníhapu tí wọn ń lu hapu wọn. Wọ́n ń kọrin titun kan níwájú ìtẹ́ náà ati níwájú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin ati àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun. Kò sí ẹni tí ó lè mọ orin náà àfi àwọn ọ̀kẹ́ meje ó lé ẹgbaaji (144,000) eniyan tí a ti rà pada ninu ayé. Àwọn ni àwọn tí kò fi obinrin ba ara wọn jẹ́, nítorí wọn kò bá obinrin lòpọ̀ rí. Àwọn yìí ni wọ́n ń tẹ̀lé Ọ̀dọ́ Aguntan náà káàkiri ibi gbogbo tí ó bá ń lọ. Àwọn ni a ti rà pada láti inú ayé, wọ́n dàbí èso àkọ́so fún Ọlọrun ati fún Ọ̀dọ́ Aguntan. Ọ̀rọ̀ èké kankan kò sí ní ẹnu wọn. Kò sí àléébù ninu ìgbé-ayé wọn. Mo tún rí angẹli mìíràn tí ń fò lágbedeméjì ọ̀run. Ó mú ìyìn rere ayérayé lọ́wọ́ láti kéde rẹ̀ fún àwọn tí wọ́n wà ninu ayé, ninu gbogbo ẹ̀yà ati gbogbo orílẹ̀-èdè. Ó bá kígbe pé, “Ẹ bẹ̀rù Ọlọrun kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí àkókò ìdájọ́ rẹ̀ dé! Ẹ júbà ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé, òkun ati gbogbo orísun omi.” Angẹli mìíràn tẹ̀lé ti àkọ́kọ́, ó ní, “Ó ti tú! Babiloni ìlú ńlá nnì ti tú! Ìlú tí ó fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní ọtí àgbèrè rẹ̀ mu, tí ó mú ibinu Ọlọrun wá, ó ti tú!” Angẹli kẹta wá tẹ̀lé wọn. Ó kígbe pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá júbà ẹranko náà ati ère rẹ̀, tí ó gba àmì rẹ̀ siwaju rẹ̀ tabi sí ọwọ́ rẹ̀, yóo mu ninu ògidì ọtí ibinu Ọlọrun, tí ó wà ninu ife ibinu rẹ̀. Olúwarẹ̀ yóo joró ninu iná àjóòkú níwájú àwọn angẹli mímọ́ ati Ọ̀dọ́ Aguntan. Èéfín iná oró àwọn tí wọ́n bá júbà ẹranko náà ati ère rẹ̀, tí wọ́n gba àmì orúkọ rẹ̀, yóo máa rú títí lae. Kò ní rọlẹ̀ tọ̀sán-tòru.” Èyí mú kí ó di dandan fún àwọn eniyan Ọlọrun, tí wọn ń pa àṣẹ Ọlọrun mọ́, tí wọ́n sì dúró ninu igbagbọ Jesu láti ní ìfaradà. Mo gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá tí ó sọ pé, “Kọ ọ́ sílẹ̀! Àwọn òkú tí wọ́n kú ninu Oluwa láti àkókò yìí lọ ṣe oríire.” Ẹ̀mí jẹ́rìí sí i pé, “Bẹ́ẹ̀ ni dájúdájú, nítorí wọn yóo sinmi ninu làálàá wọn, nítorí iṣẹ́ wọn yóo máa tọ̀ wọ́n lẹ́yìn.” Mo wá rí ìkùukùu funfun. Ẹnìkan tí ó dàbí ọmọ eniyan jókòó lórí ìkùukùu náà. Ó dé adé wúrà. Ó mú dòjé tí ó mú lọ́wọ́. Angẹli mìíràn jáde láti inú Tẹmpili wá, ó kígbe sí ẹni tí ó jókòó lórí ìkùukùu, pé, “Iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ fún dòjé rẹ; àkókò ìkórè tó: ilé ayé ti tó kórè.” Ẹni tí ó jókòó lórí ìkùukùu náà bá ti dòjé rẹ̀ bọ ilé ayé, ni ó bá kórè ayé. Angẹli mìíràn tún jáde wá láti inú Tẹmpili ní ọ̀run, tí òun náà tún mú dòjé mímú lọ́wọ́. Angẹli mìíràn wá ti ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ ìrúbọ wá, òun ni ó ní àṣẹ lórí iná. Ó kígbe sí angẹli tí ó ní dòjé mímú pé, “Iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ fún dòjé mímú rẹ. Kó èso àwọn igi eléso ilé ayé jọ, nítorí pé wọ́n ti pọ́n.” Ni angẹli tí ó ní dòjé náà bá ti dòjé rẹ̀ bọ inú ilé ayé, ó bá kó èso àjàrà ayé jọ, ó dà wọ́n sí ibi ìfúntí ibinu ńlá Ọlọrun. Lẹ́yìn odi ìlú ni ìfúntí náà wà. Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tẹ èso ninu rẹ̀, ẹ̀jẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí yọ jáde láti inú ìfúntí náà. Jíjìn rẹ̀ mu ẹṣin dé ọrùn, ó sì gba ilẹ̀ lọ ní nǹkan bí igba ibùsọ̀. Mo tún rí ohun abàmì mìíràn ní ọ̀run, ohun ńlá ati ohun ìyanu: àwọn angẹli meje tí àjàkálẹ̀ àrùn meje ti ìkẹyìn wà ní ìkáwọ́ wọn, nítorí pé àwọn ni wọ́n mú ibinu Ọlọrun wá sí òpin. Mo tún rí ohun tí ó dàbí òkun dígí tí iná wà ninu rẹ̀. Àwọn kan dúró lẹ́bàá òkun dígí náà, àwọn tí wọ́n ti ṣẹgun ẹranko náà ati ère rẹ̀, ati iye orúkọ rẹ̀. Wọ́n mú hapu Ọlọrun lọ́wọ́, wọ́n ń kọ orin Mose iranṣẹ Ọlọrun ati orin Ọ̀dọ́ Aguntan náà pé, “Iṣẹ́ ńlá ati iṣẹ́ ìyanu ni iṣẹ́ rẹ, Oluwa, Ọlọrun Olodumare. Òdodo ati òtítọ́ ni àwọn iṣẹ́ ọnà rẹ, Ọba àwọn orílẹ̀-èdè. Ta ni kò ní bẹ̀rù rẹ, Oluwa? Ta ni kò ní fi ògo fún orúkọ rẹ? Nítorí ìwọ nìkan ni ó pé, nítorí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo wá, wọn yóo júbà níwájú rẹ, nítorí òdodo rẹ farahàn gbangba.” Lẹ́yìn èyí mo tún rí Tẹmpili tí ó ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run. Àgọ́-Ẹ̀rí wà ninu rẹ̀. Àwọn angẹli meje tí wọ́n ní àjàkálẹ̀ àrùn meje níkàáwọ́ jáde láti inú Tẹmpili náà wá, wọ́n wọ aṣọ funfun tí ó ń tàn bí ìmọ́lẹ̀. Wúrà ni wọ́n fi ṣe ìgbàyà wọn. Ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀dá alààyè náà fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn angẹli meje náà ní àwo wúrà kéékèèké kọ̀ọ̀kan, àwọn àwo wúrà yìí kún fún ibinu Ọlọrun, ẹni tí ó wà láàyè lae ati laelae. Inú Tẹmpili wá kún fún èéfín ògo Ọlọrun ati ti agbára rẹ̀. Kò sí ẹni tí ó lè wọ inú Tẹmpili títí tí àwọn àjàkálẹ̀ àrùn meje ti àwọn angẹli meje náà fi parí. Mo gbọ́ ohùn líle kan láti inú Tẹmpili tí ó sọ fún àwọn angẹli meje náà pé, “Ẹ lọ da àwọn àwo meje tí ó kún fún ibinu Ọlọrun sinu ayé.” Angẹli kinni lọ, ó bá da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sinu ayé. Ni egbò rírà tí ń rùn bá dà bo àwọn tí wọ́n ní àmì ẹranko náà ní ara, tí wọ́n sì ń júbà ère rẹ̀. Angẹli keji da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sinu òkun, ni òkun bá di ẹ̀jẹ̀, bí ẹ̀jẹ̀ ara òkú, gbogbo nǹkan ẹlẹ́mìí tí ó wà ninu òkun sì kú. Angẹli kẹta da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sinu odò ati sinu ìsun omi, ó bá di ẹ̀jẹ̀. Mo wá gbọ́ ohùn angẹli tí omi wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ tí ó sọ pé, “Olódodo ni ọ́ fún ìdájọ́ rẹ wọnyi, ìwọ tí ó wà, tí ó ti wà, ìwọ Ẹni Mímọ́! Wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ àwọn eniyan rẹ ati àwọn wolii rẹ sílẹ̀, nítorí náà o fún wọn ní ẹ̀jẹ̀ mu. Ohun tí ó yẹ wọ́n ni o fún wọn!” Mo bá gbọ́ tí pẹpẹ ìrúbọ wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa, Ọlọrun, Olodumare, òtítọ́ ati òdodo ni ìdájọ́ rẹ.” Angẹli kẹrin da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ nù sórí oòrùn, a bá fún un lágbára láti máa jó eniyan bí iná. Oòrùn bẹ̀rẹ̀ sí jó àwọn eniyan bí iná ńlá, wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí orúkọ Ọlọrun tí ó ní àṣẹ lórí àwọn àjàkálẹ̀ àrùn wọnyi, dípò kí wọ́n ronupiwada, kí wọ́n fi ògo fún un. Angẹli karun-un da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sórí ìtẹ́ ẹranko náà, ó bá sọ ìjọba rẹ̀ di òkùnkùn. Àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí gé ara wọn láhọ́n jẹ nítorí ìrora wọn, wọn bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun ọ̀run nítorí ìrora wọn ati nítorí egbò ara wọn, dípò kí wọ́n ronupiwada fún ohun tí wọ́n ti ṣe. Angẹli kẹfa da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sórí odò ńlá tí wọn ń pè ní Yufurate, ni omi rẹ̀ bá gbẹ láti fi ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn ọba tí ń bọ̀ láti ìhà ìlà oòrùn. Mo wá rí àwọn ẹ̀mí burúkú mẹta kan, wọ́n dàbí ọ̀pọ̀lọ́ ní ẹnu Ẹranko Ewèlè náà, ati ní ẹnu wolii èké náà. Ẹ̀mí Èṣù ni àwọn ẹ̀mí náà, wọ́n sì lè ṣe ohun abàmì. Wọ́n jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba ní gbogbo ayé, láti kó wọn jọ fún ogun ní ọjọ́ ńlá ti Ọlọrun alágbára jùlọ. “Bí olè ni mò ń bọ̀. Ẹni tí ó bá ń ṣọ́nà ṣe oríire, tí olúwarẹ̀ wọ aṣọ rẹ̀, kí ó má baà sí ní ìhòòhò, kí ojú má baà tì í níwájú àwọn eniyan.” Ó bá kó àwọn ọba wọnyi jọ sí ibìkan tí ń jẹ́ Amagedoni ní èdè Heberu. Angẹli keje da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sinu afẹ́fẹ́. Ẹnìkan bá fi ohùn líle sọ̀rọ̀ láti ibi ìtẹ́ tí ó wà ninu Tẹmpili, ó ní, “Ó ti parí!” Ni mànàmáná bá bẹ̀rẹ̀ sí kọ, ààrá ń sán, ilẹ̀ ń mì tìtì, tóbẹ́ẹ̀ tí kò sí irú rẹ̀ rí láti ìgbà tí eniyan ti dé orí ilẹ̀ ayé. Ìlú ńlá náà bá pín sí mẹta. Gbogbo ìlú àwọn orílẹ̀-èdè bá tú. Babiloni ìlú ńlá náà kò bọ́ lọ́wọ́ ìdájọ́ Ọlọrun, Ọlọrun jẹ́ kí ó mu ninu ìkorò ibinu rẹ̀. Omi bo gbogbo àwọn erékùṣù, a kò sì rí ẹyọ òkè kan mọ́. Yìnyín ńláńlá tí ó tóbi tó ọlọ ata wá bẹ̀rẹ̀ sí bọ́ lu eniyan láti ojú ọ̀run. Àwọn eniyan wá ń sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun nítorí ìparun tí yìnyín yìí ń fà, nítorí ó ń ṣe ọpọlọpọ ijamba. Ọ̀kan ninu àwọn angẹli meje tí wọ́n ní àwo meje náà tọ̀ mí wá, ó ní, “Wá kí n fi ìdájọ́ tí ń bọ̀ sórí gbajúmọ̀ aṣẹ́wó náà hàn ọ́, ìlú tí a kọ́ sójú ọpọlọpọ omi. Àwọn ọba ayé ti ṣe àgbèrè pẹlu rẹ̀, àwọn tí ń gbé inú ayé ti mu ninu ọtí àgbèrè rẹ̀.” Ẹ̀mí gbé mi, ni angẹli yìí bá gbé mi lọ sinu aṣálẹ̀. Níbẹ̀ ni mo ti rí obinrin tí ó gun ẹranko pupa kan, tí àwọn orúkọ àfojúdi kún ara rẹ̀. Ẹranko náà ní orí meje ati ìwo mẹ́wàá. Aṣọ àlàárì ati aṣọ pupa ni obinrin náà wọ̀. Ó fi ọ̀ṣọ́ wúrà sára pẹlu oríṣìíríṣìí ìlẹ̀kẹ̀ olówó iyebíye. Ó mú ife wúrà lọ́wọ́, ife yìí kún fún ẹ̀gbin ati ohun ìbàjẹ́ àgbèrè rẹ̀. Orúkọ àṣírí kan wà níwájú rẹ̀, ìtumọ̀ rẹ̀ ni: “Babiloni ìlú ńlá, ìyá àwọn àgbèrè ati oríṣìíríṣìí ohun ẹ̀gbin ayé.” Mo wá rí obinrin náà tí ó ti mu ẹ̀jẹ̀ àwọn eniyan Ọlọrun ní àmuyó, pẹlu ẹ̀jẹ̀ àwọn tí wọ́n jẹ́rìí igbagbọ ninu Jesu. Ìyanu ńlá ni ó jẹ́ fún mi nígbà tí mo rí obinrin náà. Angẹli náà bi mí pé, “Kí ni ó yà ọ́ lẹ́nu? N óo sọ àṣírí obinrin náà fún ọ ati ti ẹranko tí ó gùn, tí ó ní orí meje ati ìwo mẹ́wàá. Ẹranko tí o rí yìí ti wà láàyè nígbà kan rí, ṣugbọn kò sí láàyè mọ́ nisinsinyii. Ṣugbọn ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò, tí yóo gòkè wá láti inú ọ̀gbun jíjìn, tí yóo wá lọ sí ibi ègbé. Nígbà tí wọ́n bá rí ẹranko náà ẹnu yóo ya àwọn tí ó ń gbé orí ilẹ̀ ayé, tí a kò kọ orúkọ wọn sinu ìwé ìyè láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá, nítorí ó ti wà láàyè, ṣugbọn kò sí láàyè nisinsinyii, ṣugbọn yóo tún pada yè. “Ọ̀rọ̀ yìí gba ọgbọ́n. Orí meje tí ẹranko náà ní jẹ́ òkè meje tí obinrin náà jókòó lé lórí. Wọ́n tún jẹ́ ọba meje. Marun-un ninu wọn ti kú. Ọ̀kan wà lórí oyè nisinsinyii. Ọ̀kan yòókù kò ì tíì jẹ. Nígbà tí ó bá jọba, àkókò díẹ̀ ni yóo ṣe lórí oyè. Ẹranko tí ó ti wà láàyè rí, tí kò sí mọ́, ni ẹkẹjọ, ṣugbọn ó wà ninu àwọn meje tí ń lọ sinu ègbé. “Àwọn ìwo mẹ́wàá tí o rí jẹ́ ọba mẹ́wàá. Ṣugbọn wọn kò ì tíì joyè. Wọn óo gba àṣẹ fún wakati kan, àwọn ati ẹranko náà ni yóo jọ lo àṣẹ náà. Ète kanṣoṣo ni wọ́n ní. Wọn yóo fi agbára wọn ati àṣẹ wọn fún ẹranko náà. Wọn yóo bá Ọ̀dọ́ Aguntan náà jagun, ṣugbọn Ọ̀dọ́ Aguntan náà yóo ṣẹgun wọn nítorí pé òun ni Oluwa àwọn oluwa ati Ọba àwọn ọba. Àwọn tí wọ́n wà pẹlu Ọ̀dọ́ Aguntan náà ninu ìjà ati ìṣẹ́gun náà ni àwọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, tí a pè, tí a sì yàn.” Ó tún wí fún mi pé, “Àwọn omi tí o rí níbi tí aṣẹ́wó náà ti jókòó ni àwọn eniyan ati gbogbo orílẹ̀-èdè. Nígbà tí ó bá yá, àwọn ìwo mẹ́wàá tí o rí yìí ati ẹranko náà, yóo kórìíra aṣẹ́wó náà, wọn óo tú u sí ìhòòhò, wọn óo bá fi í sílẹ̀ ní ahoro. Wọn óo jẹ ẹran-ara rẹ̀, wọn óo bá dá iná sun ún títí yóo fi jóná ráúráú. Nítorí Ọlọrun fi sí ọkàn wọn láti ní ète kan náà, pé àwọn yóo fi ìjọba àwọn fún ẹranko náà títí gbogbo ohun tí Ọlọrun ti sọ yóo fi ṣẹ. “Obinrin tí o rí ni ìlú ńlá náà tí ó ń pàṣẹ lórí àwọn ọba ilẹ̀ ayé.” Lẹ́yìn èyí mo tún rí angẹli tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ bọ̀. Ó ní àṣẹ ńlá. Gbogbo ayé mọ́lẹ̀ nítorí ẹwà ògo rẹ̀. Ó wá kígbe pé, “Ó tú! Babiloni ìlú ńlá tú! Ó wá di ibi tí àwọn àǹjọ̀nnú ń gbé, tí ẹ̀mí Èṣù oríṣìíríṣìí ń pààrà, tí oríṣìíríṣìí ẹyẹkẹ́yẹ ń kiri. Nítorí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ti mu àmuyó ninu ọtí àgbèrè rẹ̀, ọtí tí ó fa ibinu Ọlọrun. Àwọn ọba ilẹ̀ ayé ti ṣe àgbèrè pẹlu rẹ̀, àwọn oníṣòwò ilẹ̀ ayé ti di olówó nípa ìwà jayéjayé rẹ̀.” Mo tún gbọ́ ohùn mìíràn láti ọ̀run tí ó sọ pé, “Ẹ jáde kúrò ninu rẹ̀, ẹ̀yin eniyan mi, kí ẹ má baà ní ìpín ninu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ẹ má baà fara gbá ninu ìjìyà rẹ̀. Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ga dé ọ̀run, Ọlọrun kò gbàgbé àìṣedéédé rẹ̀. Ṣe fún un bí òun náà ti ṣe fún eniyan. Gbẹ̀san lára rẹ̀ ní ìlọ́po meji ìwà rẹ̀. Ife tí ó fi ń bu ọtí fún eniyan ni kí o fi bu ọtí tí ó le ní ìlọ́po meji fún òun alára. Bí ó ti ṣe ń jẹ ọlá, tí ó ń jẹ ayé tẹ́lẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kí o fún un ní ìrora ati ìbànújẹ́. Ó ń sọ ní ọkàn rẹ̀ pé, ‘Ọba orí ìtẹ́ ni mí, èmi kì í ṣe opó, ojú mi kò ní rí ìbànújẹ́.’ Nítorí èyí, ní ọjọ́ kan náà ni oríṣìíríṣìí òfò yóo dé bá a, ati àjàkálẹ̀ àrùn, ati ọ̀fọ̀, ati ìyàn. Iná yóo tún jó o ní àjórun, nítorí alágbára ni Oluwa Ọlọrun tí ó ti ń ṣe ìdájọ́ fún un.” Àwọn ọba ayé ati àwọn tí wọ́n ti bá a ṣe àgbèrè, tí wọ́n ti ń bá a jayé yóo sunkún, wọn óo ṣọ̀fọ̀ lé e lórí nígbà tí wọ́n bá rí èéfín iná tí ń jó o. Wọn óo dúró ní òkèèrè nítorí ẹ̀rù tí yóo máa bà wọ́n nítorí ìrora rẹ̀. Wọn óo sọ pé, “Ó ṣe! Ó ṣe fún ọ! Ìlú ńlá, Babiloni ìlú alágbára! Nítorí ní wakati kan ni ìparun dé bá ọ.” Àwọn oníṣòwò ayé yóo sunkún, wọn yóo ṣọ̀fọ̀ lé e lórí, nítorí wọn kò rí ẹni ra ọjà wọn mọ́; àwọn nǹkan bíi: Wúrà, fadaka, òkúta iyebíye, oríṣìíríṣìí ìlẹ̀kẹ̀, aṣọ funfun ati àlàárì, ati sányán ati aṣọ pupa; oríṣìíríṣìí pákó, ati àwọn ohun èèlò tí a fi eyín erin, igi iyebíye, idẹ, irin, ati òkúta ṣe; oríṣìíríṣìí òróró ìkunra, turari ati òjíá, ọtí, òróró olifi, ọkà, ati àgbàdo, ẹṣin, kẹ̀kẹ́ ogun, ẹrú, àní ẹ̀mí eniyan. Wọ́n ní, “Èso tí o fẹ́ràn kò sí mọ́, gbogbo ìgbé-ayé fàájì ati ti ìdẹ̀ra ti bọ́ lọ́wọ́ rẹ, o kò tún ní rí irú rẹ̀ mọ́.” Àwọn oníṣòwò wọnyi, tí wọ́n ti di olówó ninu rẹ̀ yóo dúró ní òkèèrè nígbà tí ẹ̀rù bá ń bà wọ́n nítorí ìrora rẹ̀, wọn óo máa sunkún, wọn óo máa ṣọ̀fọ̀. Wọn óo máa wí pé, “Ó ṣe! Ó ṣe fún ìlú ńlá náà! Ìlú tí ó wọ aṣọ funfun, ati aṣọ àlàárì ati aṣọ pupa. Ìlú tí wúrà pọ̀ níbẹ̀ ati òkúta iyebíye ati ìlẹ̀kẹ̀! Ní wakati kan péré ni gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ run!” Nígbà náà ni gbogbo ọ̀gá àwọn awakọ̀ ojú omi, ati gbogbo àwọn tí ó ń wọ ọkọ̀ ati àwọn atukọ̀ ati àwọn tí iṣẹ́ wọn jẹ mọ́ ojú omi òkun lọ dúró ní òkèèrè. Wọ́n ń kígbe sókè nígbà tí wọ́n rí èéfín iná tí ń jó ìlú náà. Wọ́n wá ń sọ pé, “Ìlú wo ni ó dàbí ìlú ńlá yìí?” Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bu yẹ̀ẹ̀pẹ̀ sórí ara wọn, wọ́n ń sunkún, wọ́n ń ṣọ̀fọ̀. Wọ́n ní, “Ó ṣe! Ó ṣe fún ìlú ńlá náà, níbi tí gbogbo àwọn tí wọn ní ọkọ̀ lójú òkun ti di ọlọ́rọ̀ nípa ọrọ̀ rẹ̀, nítorí ní wakati kan ó ti di ahoro! Ọ̀run, yọ̀ lórí rẹ̀! Ẹ yọ̀, ẹ̀yin eniyan Ọlọrun, ẹ̀yin aposteli, ati ẹ̀yin wolii, nítorí Ọlọrun ti ṣe ìdájọ́ fún un bí òun náà ti ṣe fún yín!” Ọ̀kan ninu àwọn angẹli alágbára bá gbé òkúta tí ó tóbi bí ọlọ ògì, ó jù ú sinu òkun, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ ni a óo fi tagbára-tagbára sọ Babiloni ìlú ńlá náà mọ́lẹ̀ tí a kò ní rí i mọ́. A kò tún ní gbọ́ ohùn fèrè ati ti àwọn olórin tabi ti ohùn ìlù ati ti ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ ninu rẹ mọ́. A kò ní tún rí àwọn oníṣọ̀nà fún iṣẹ́ ọnà kan ninu rẹ mọ́. A kò ní gbọ́ ìró ọlọ ninu rẹ mọ́. Iná àtùpà kan kò ní tàn ninu rẹ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní gbọ́ ohùn ọkọ iyawo ati ti iyawo ninu rẹ mọ́. Nígbà kan rí àwọn oníṣòwò rẹ ni àwọn gbajúmọ̀ ninu ayé. O fi ìwà àjẹ́ tan gbogbo orílẹ̀-èdè jẹ.” Ninu rẹ ni a ti rí ẹ̀jẹ̀ àwọn wolii ati ẹ̀jẹ̀ àwọn eniyan Ọlọrun, ati gbogbo àwọn ẹni tí wọ́n pa lórí ilẹ̀ ayé. Lẹ́yìn èyí mo gbọ́ ohùn kan bí igbe ọ̀pọ̀ eniyan ní ọ̀run, tí ń sọ pé, “Haleluya! Ìgbàlà ati ògo ati agbára ni ti Ọlọrun wa. Òtítọ́ ati òdodo ni ìdájọ́ rẹ̀. Nítorí ó ti dájọ́ fún gbajúmọ̀ aṣẹ́wó náà, tí ó fi àgbèrè rẹ̀ ba ayé jẹ́. Ó ti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn iranṣẹ rẹ̀ lára rẹ̀.” Wọ́n tún wí lẹẹkeji pé, “Haleluya! Èéfín rẹ̀ ń gòkè lae ati laelae.” Àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun náà ati àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà bá dojúbolẹ̀, wọ́n júbà Ọlọrun tí ó jókòó lórí ìtẹ́. Wọ́n ní, “Amin! Haleluya!” Ẹnìkan fọhùn láti orí ìtẹ́ náà, ó ní, “Ẹ yin Ọlọrun wa, gbogbo ẹ̀yin ìran rẹ̀, ati gbogbo ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù rẹ̀, ẹ̀yin mẹ̀kúnnù ati ẹ̀yin eniyan pataki.” Mo tún gbọ́ ohùn kan bí ohùn ọ̀pọ̀ eniyan, ati bí ìró ọpọlọpọ omi, ati bí sísán ààrá líle, ohùn náà sọ pé, “Haleluya! Nítorí Oluwa Ọlọrun wa, Olodumare jọba. Ẹ jẹ́ kí á yọ̀, kí inú wa dùn, ẹ jẹ́ kí á fi ògo fún un, nítorí ó tó àkókò igbeyawo Ọ̀dọ́ Aguntan náà. Iyawo rẹ̀ sì ti ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ dè é. A fún un ní aṣọ funfun tí ń dán, tí ó sì mọ́. Aṣọ funfun náà ni iṣẹ́ òdodo àwọn eniyan Ọlọrun.” Ó sọ fún mi pé, “Kọ ọ́ sílẹ̀: àwọn tí a pè sí àsè igbeyawo ti Ọ̀dọ́ Aguntan náà ṣe oríire.” Ó tún sọ fún mi pé, “Òdodo ọ̀rọ̀ Ọlọrun ni ọ̀rọ̀ wọnyi.” Ni mo bá dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀, mo júbà rẹ̀. Ó bá sọ fún mi pé, “Èèwọ̀! Má ṣe bẹ́ẹ̀! Iranṣẹ bí ìwọ ati àwọn arakunrin rẹ, tí wọ́n jẹ́rìí igbagbọ ninu Jesu, ni èmi náà. Ọlọrun ni kí o júbà.” Nítorí ẹ̀mí tí ó mú kí eniyan jẹ́rìí igbagbọ ninu Jesu ni ẹ̀mí tí ó wà ninu wolii. Mo rí ọ̀run tí ó ṣí sílẹ̀. Mo wá rí ẹṣin funfun kan. Orúkọ ẹni tí ó gùn ún ni Olódodo ati Olóòótọ́, nítorí pẹlu òdodo ni ó ń ṣe ìdájọ́, tí ó sì ń jagun. Ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́ iná. Ó dé adé pupọ tí a kọ orúkọ sí, orúkọ tí ẹnikẹ́ni kò mọ̀ àfi òun alára. Ó wọ ẹ̀wù tí a rẹ sinu ẹ̀jẹ̀. Orúkọ tí à ń pè é ni Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Àwọn ọmọ-ogun ọ̀run ń tẹ̀lé e, wọ́n gun ẹṣin funfun. Aṣọ tí wọ́n wọ̀ funfun, ó sì mọ́. Idà mímú yọ jáde ní ẹnu rẹ̀, tí yóo fi ṣẹgun àwọn orílẹ̀-èdè, nítorí òun ni yóo jọba lórí wọn pẹlu ọ̀pá irin. Òun ni yóo pọn ọtí ibinu ati ti ẹ̀san Ọlọrun Olodumare. A kọ orúkọ kan sára ẹ̀wù ati sí itan rẹ̀ pé: “Ọba àwọn ọba ati Oluwa àwọn olúwa.” Mo tún rí angẹli kan tí ó dúró ninu oòrùn, ó kígbe sí àwọn ẹyẹ tí ń fò lágbedeméjì ọ̀run pé, “Ẹ wá péjọ sí ibi àsè ńlá Ọlọrun, kí ẹ lè jẹ ẹran-ara àwọn ọba ati ti àwọn ọ̀gágun, ati ti àwọn alágbára, ati ẹran ẹṣin ati ti àwọn tí wọ́n gùn wọ́n, ati ẹran-ara àwọn òmìnira ati ti ẹrú, ti àwọn mẹ̀kúnnù ati ti àwọn ọlọ́lá.” Mo wá rí ẹranko náà ati àwọn ọba ilé ayé ati àwọn ọmọ-ogun wọn. Wọ́n péjọ láti bá ẹni tí ó gun ẹṣin funfun náà ati àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ jagun. A mú ẹranko náà lẹ́rú, pẹlu wolii èké tí ó ń ṣe iṣẹ́ abàmì níwájú rẹ̀, tí ó ti tan àwọn tí wọ́n gba àmì ẹranko náà jẹ, ati àwọn tí wọ́n júbà ère rẹ̀. A wá gbé àwọn mejeeji láàyè, a sọ wọ́n sinu adágún iná tí a fi imí-ọjọ́ dá. Wọ́n fi idà tí ó wà lẹ́nu ẹni tí ó gun ẹṣin funfun pa àwọn yòókù. Gbogbo àwọn ẹyẹ bá ń jẹ ẹran-ara wọn ní àjẹrankùn. Mo wá rí angẹli kan tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, ó mú kọ́kọ́rọ́ kànga tí ó jìn pupọ náà lọ́wọ́ ati ẹ̀wọ̀n gígùn. Ó bá ki Ẹranko Ewèlè náà mọ́lẹ̀, ejò àtijọ́ náà tíí ṣe Èṣù tabi Satani, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é fún ẹgbẹrun ọdún. Ó bá jù ú sinu kànga tí ó jìn pupọ náà, ó pa ìdérí rẹ̀ dé mọ́ ọn lórí. Ó bá fi èdìdì dì í kí ó má baà tan àwọn eniyan jẹ mọ́ títí ẹgbẹrun ọdún yóo fi parí. Lẹ́yìn náà, a óo dá a sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. Lẹ́yìn náà, mo rí àwọn ìtẹ́ kan tí eniyan jókòó lórí wọn. A fún àwọn eniyan wọnyi láṣẹ láti ṣe ìdájọ́. Àwọn ni ọkàn àwọn tí wọ́n ti bẹ́ lórí nítorí ẹ̀rí tí wọ́n jẹ́ nípa Jesu ati nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Àwọn ni wọ́n kò júbà ẹranko náà tabi ère rẹ̀, wọn kò sì gba àmì rẹ̀ siwaju wọn tabi sí ọwọ́ wọn. Wọ́n tún wà láàyè, wọ́n sì jọba pẹlu Kristi fún ẹgbẹrun ọdún. Àwọn òkú yòókù kò jí dìde títí òpin ẹgbẹrun ọdún. Èyí ni ajinde kinni. Àwọn eniyan Ọlọrun tí ó bá ní ìpín ninu ajinde kinni ṣe oríire. Ikú keji kò ní ní àṣẹ lórí wọn. Wọn óo jẹ́ alufaa Ọlọrun ati ti Kristi, wọn óo sì jọba pẹlu rẹ̀ fún ẹgbẹrun ọdún. Nígbà tí ẹgbẹrun ọdún bá parí a óo tú Satani sílẹ̀ ninu ẹ̀wọ̀n tí ó ti wà. Yóo wá tún jáde lọ láti máa tan àwọn eniyan jẹ ní igun mẹrẹẹrin ilẹ̀ ayé. Yóo kó gbogbo eniyan Gogu ati Magogu jọ láti jagun, wọn óo pọ̀ bí iyanrìn etí òkun. Wọ́n gba gbogbo ìbú ilẹ̀ ayé, wọ́n wá yí àwọn eniyan Ọlọrun ká ati ìlú tí Ọlọrun fẹ́ràn. Ni iná bá sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run, ó bá jó wọn run patapata. A bá ju Èṣù tí ó ń tàn wọ́n jẹ sinu adágún iná tí a fi imí-ọjọ́ dá, níbi tí ẹranko náà ati wolii èké náà wà, tí wọn yóo máa joró tọ̀sán-tòru lae ati laelae. Mo wá rí ìtẹ́ funfun ńlá kan ati ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀. Ayé ati ọ̀run sálọ fún un, a kò rí ààyè fún wọn mọ́. Mo rí òkú àwọn ọlọ́lá ati ti àwọn mẹ̀kúnnù, tí wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ náà. Àwọn ìwé àkọsílẹ̀ wà ní ṣíṣí. Ìwé mìíràn tún wà ní ṣíṣí, tí orúkọ àwọn alààyè wà ninu rẹ̀. A wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìdájọ́ àwọn òkú gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn tí ó wà ninu àwọn ìwé àkọsílẹ̀. Gbogbo àwọn tí wọ́n kú sinu òkun tún jáde sókè. Gbogbo òkú tí ó wà níkàáwọ́ ikú ati àwọn tí wọ́n wà ní ipò òkú ni wọ́n tún jáde. A wá ṣe ìdájọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀. Ni a bá ju ikú ati ipò òkú sinu adágún iná. Adágún iná yìí ni ikú keji. Ẹnikẹ́ni tí kò bá sí orúkọ rẹ̀ ninu ìwé ìyè, a óo sọ ọ́ sinu adágún iná. Mo rí ọ̀run titun ati ayé titun, ayé ti àkọ́kọ́ ti kọjá lọ. Òkun kò sì sí mọ́. Lẹ́yìn náà mo rí ìlú mímọ́ náà, Jerusalẹmu titun, tí ó ń ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun sọ̀kalẹ̀ láti òkè wá. A ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ bí ìgbà tí a bá ṣe iyawo lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọkọ rẹ̀. Mo wá gbọ́ ohùn líle kan láti orí ìtẹ́ náà wá tí ó wí pé, “Ọlọrun pàgọ́ sí ààrin àwọn eniyan, yóo máa bá wọn gbé, wọn yóo jẹ́ eniyan rẹ̀, Ọlọrun pàápàá yóo wà pẹlu wọn; yóo nu gbogbo omijé nù ní ojú wọn. Kò ní sí ikú mọ́, tabi ọ̀fọ̀ tabi ẹkún tabi ìrora. Nítorí àwọn ohun ti àtijọ́ ti kọjá lọ.” Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà sọ pé, “Mò ń sọ ohun gbogbo di titun.” Ó ní, “Kọ ọ́ sílẹ̀, nítorí òdodo ọ̀rọ̀ ati òtítọ́ ni àwọn ọ̀rọ̀ yìí.” Ó ní, “Ó parí! Èmi ni Alfa ati Omega, ìbẹ̀rẹ̀ ati òpin. N óo fún ẹni tí òùngbẹ bá ń gbẹ ní omi mu láti inú kànga omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́. Ẹni tí ó bá ṣẹgun ni yóo jogún nǹkan wọnyi. N óo máa jẹ́ Ọlọrun rẹ̀, òun náà yóo sì máa jẹ́ ọmọ mi. Ṣugbọn àwọn ojo, àwọn alaigbagbọ, àwọn ẹlẹ́gbin, àwọn apànìyàn, àwọn àgbèrè, àwọn oṣó, àwọn abọ̀rìṣà, ati gbogbo àwọn èké ni yóo ní ìpín wọn ninu adágún iná tí ń jó, tí a fi imí-ọjọ́ dá. Èyí ni ikú keji.” Ọ̀kan ninu àwọn angẹli meje tí ó mú àwo meje lọ́wọ́, tí ìparun ìkẹyìn meje wà ninu wọn, ó wá bá mi sọ̀rọ̀. Ó ní “Wá, n óo fi iyawo Ọ̀dọ́ Aguntan hàn ọ́.” Ó bá gbé mi ninu ẹ̀mí lọ sí orí òkè ńlá kan tí ó ga, ó fi Jerusalẹmu ìlú mímọ́ náà hàn mí, tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ bọ̀. Ó ń bọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Ògo Ọlọrun ń tàn lára rẹ̀. Ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ dàbí ti òkúta iyebíye. Ẹwà rẹ̀ dàbí ti òkúta iyebíye tí ó mọ́lẹ̀ gaara. Odi ìlú náà nípọn, ó sì ga. Ó ní ìlẹ̀kùn mejila, àwọn angẹli mejila wà níbi àwọn ìlẹ̀kùn mejila náà. A kọ àwọn orúkọ ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli mejila sí ara àwọn ìlẹ̀kùn mejila náà. Ìlẹ̀kùn mẹta wà ní ìhà ìlà oòrùn, mẹta wà ní ìhà àríwá, mẹta wà ni ìhà gúsù, mẹta wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn. Odi ìlú náà ní ìpìlẹ̀ mejila. Orúkọ mejila ti àwọn aposteli mejila ti Ọ̀dọ́ Aguntan wà lára wọn. Ẹni tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ mú ọ̀pá ìwọnlẹ̀ wúrà lọ́wọ́ láti fi wọn ìlú náà ati àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, ati odi rẹ̀. Igun mẹrẹẹrin ìlú náà dọ́gba, bákan náà ni gígùn rẹ̀ ati ìbú rẹ̀. Ó fi ọ̀pá ìwọnlẹ̀ náà wọn ìlú náà. Bákan náà ni gígùn rẹ̀, ati ìbú rẹ̀, ati gíga rẹ̀. Ó jẹ́ ẹẹdẹgbẹjọ (1500) ibùsọ̀. Ó wá wọn odi rẹ̀, ó ga tó igba ẹsẹ̀ ó lé ogún (220) gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n eniyan tí angẹli náà ń lò. Òkúta iyebíye ni wọ́n fi mọ odi náà. Wúrà ni gbogbo ìlú náà tí ó mọ́ gaara bíi dígí. Òkúta iyebíye oríṣìíríṣìí ni wọ́n fi ṣe ìpìlẹ̀ odi ìlú náà lọ́ṣọ̀ọ́. Ìpìlẹ̀ kinni, òkúta iyebíye oríṣìí kan, ekeji oríṣìí mìíràn, ẹkẹta oríṣìí mìíràn, ẹkẹrin, bẹ́ẹ̀; ẹkarun-un, bẹ́ẹ̀; ẹkẹfa, bẹ́ẹ̀, ekeje bẹ́ẹ̀, ẹkẹjọ, bẹ́ẹ̀, ẹkẹsan-an, bẹ́ẹ̀, ẹkẹwaa, bẹ́ẹ̀, ikọkanla bẹ́ẹ̀, ekejila náà, bẹ́ẹ̀. Òkúta tí ó dàbí ìlẹ̀kẹ̀ ni wọ́n fi ṣe àwọn ìlẹ̀kùn mejeejila ìlú náà; ẹyọ òkúta kọ̀ọ̀kan ni wọ́n fi gbẹ́ ìlẹ̀kùn kọ̀ọ̀kan. Wúrà ni wọ́n yọ́ sí títì ìlú náà. Ó mọ́ gaara bíi dígí. N kò rí Tẹmpili ninu ìlú náà. Nítorí Oluwa Ọlọrun ati Ọ̀dọ́ Aguntan ni Tẹmpili ibẹ̀. Ìlú náà kò nílò ìmọ́lẹ̀ oòrùn tabi ti òṣùpá, nítorí pé ògo Ọlọrun ni ó ń tan ìmọ́lẹ̀ sí i; Ọ̀dọ́ Aguntan ni àtùpà ibẹ̀. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa rìn ninu ìmọ́lẹ̀ rẹ̀. Àwọn ọba ilé-ayé yóo mú ọlá wọn wá sinu rẹ̀. Wọn kò ní ti àwọn ìlẹ̀kùn ìlú náà ní gbogbo ọ̀sán; òru kò sì ní sí níbẹ̀. Wọn yóo mú ẹwà ati ọlá àwọn orílẹ̀-èdè wá sí inú rẹ̀. Ohun ìdọ̀tí kan kò ní wọ inú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó bá ń ṣe ohun ẹ̀gbin tabi èké kò ní wọ ibẹ̀. Àwọn tí a ti kọ orúkọ wọn sinu ìwé ìyè Ọ̀dọ́ Aguntan nìkan ni yóo wọ ibẹ̀. Ó wá fi odò omi ìyè hàn mí, tí ó mọ́ gaara bíi dígí. Ó ń ti ibi ìtẹ́ Ọlọrun ati Ọ̀dọ́ Aguntan ṣàn wá. Ó gba ààrin títì ìlú náà. Igi ìyè kan wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún, ọ̀kan wà ní ẹ̀gbẹ́ òsì odò náà. Igi ìyè yìí ń so èso mejila, ọ̀kan ní oṣooṣù. Ewé igi náà wà fún ìwòsàn àwọn orílẹ̀-èdè. Kò ní sí ègún mọ́. Ìtẹ́ Ọlọrun ati ti Ọ̀dọ́ Aguntan yóo wà níbẹ̀. Àwọn iranṣẹ rẹ̀ yóo máa sìn ín. Wọn óo rí i lojukooju, orúkọ rẹ̀ yóo sì wà níwájú wọn. Kò ní sí òru mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní nílò ìmọ́lẹ̀ àtùpà tabi ìmọ́lẹ̀ oòrùn, nítorí Oluwa Ọlọrun wọn ni yóo jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún wọn. Wọn yóo sì máa jọba lae ati laelae. Ó tún sọ fún mi pé, “Òdodo ati òtítọ́ ni àwọn ọ̀rọ̀ yìí. Oluwa Ọlọrun tí ó mí sinu àwọn wolii rẹ̀ ni ó rán angẹli rẹ̀ pé kí ó fi àwọn ohun tí ó níláti ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ han àwọn iranṣẹ rẹ̀.” “Mò ń bọ̀ kíákíá. Ẹni tí ó bá pa àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí mọ́ ṣe oríire.” Èmi Johanu ni mo gbọ́ nǹkan wọnyi, tí mo sì rí wọn. Nígbà tí mo gbọ́, tí mo sì rí wọn, mo dojúbolẹ̀ níwájú angẹli tí ó fi wọ́n hàn mí. Ṣugbọn ó sọ fún mi pé, “Èèwọ̀! Má ṣe bẹ́ẹ̀! Iranṣẹ ẹlẹgbẹ́ rẹ ni èmi náà ati ti àwọn wolii, arakunrin rẹ, ati ti àwọn tí wọ́n ti pa àwọn ọ̀rọ̀ ìwé yìí mọ́. Ọlọrun ni kí o júbà.” Ó tún sọ fún mi pé, “Má ṣe fi èdìdì di àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ìwé yìí nítorí àkókò tí wọn yóo ṣẹ súnmọ́ tòsí. Ẹni tí ó bá ń hùwà burúkú, kí ó máa hùwà burúkú rẹ̀ bọ̀. Ẹni tí ó bá ń ṣe ohun èérí, kí ó máa ṣe ohun èérí rẹ̀ bọ̀. Ẹni tí ó bá ń hùwà rere, kí ó máa hùwà rere rẹ̀ bọ̀. Ẹni tí ó ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Ọlọrun, kí ó máa ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Ọlọrun bọ̀.” “Mò ń bọ̀ ní kíá. Èrè mi sì wà lọ́wọ́ mi, tí n óo fún ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ bá ti rí. Èmi ni Alfa ati Omega, ẹni àkọ́kọ́ ati ẹni ìkẹyìn, ìbẹ̀rẹ̀ ati òpin.” Àwọn tí wọ́n bá fọ aṣọ wọn ṣe oríire. Wọn óo ní àṣẹ láti dé ibi igi ìyè, wọn óo sì gba ẹnu ọ̀nà wọ inú ìlú mímọ́ náà. Lóde ni àwọn ajá yóo wà ati àwọn oṣó ati àwọn àgbèrè, ati àwọn apànìyàn ati àwọn abọ̀rìṣà ati àwọn tí wọ́n fẹ́ràn láti máa ṣe èké. “Èmi Jesu ni mo rán angẹli mi láti jíṣẹ́ gbogbo nǹkan wọnyi fún ẹ̀yin ìjọ. Èmi gan-an ni gbòǹgbò ati ọmọ Dafidi. Èmi ni ìràwọ̀ òwúrọ̀.” Ẹ̀mí ati Iyawo ń wí pé, “Máa bọ̀!” Ẹni tí ó gbọ́ níláti sọ pé, “Máa bọ̀.” Ẹni tí òùngbẹ bá ń gbẹ kí ó wá, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó mu omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́. Mò ń kìlọ̀ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ìwé yìí. Bí ẹnikẹ́ni bá fi nǹkankan kún un, Ọlọrun yóo fi kún àwọn ìyà rẹ̀ tí a ti kọ sinu ìwé yìí. Bí ẹnikẹ́ni bá mú nǹkankan kúrò ninu ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ìwé yìí, Ọlọrun yóo mú ìpín rẹ̀ kúrò lára igi ìyè ati kúrò ninu ìlú mímọ́ náà, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sílẹ̀ ninu ìwé yìí. Ẹni tí ó jẹ́rìí sí nǹkan wọnyi sọ pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, tètè máa bọ̀. Amin! Máa bọ̀, Oluwa Jesu.” Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu kí ó wà pẹlu gbogbo yín.