Ìsun kan wa tó kún fẹ́jẹ̀ Mo ti ní Jésù lọ́rẹ̀ Enìkan nbẹ tó fẹ́ràn wa Gba ayé mi, Olúwa Olùgbàlà gbóhùn mi Árẹ̀ mú Ọ, ọkàn re pòrurù Bó ti dùn láti gba Jésù Wá sọ́dọ̀ Jésù, má ṣe dúró Ẹkún kò le gbà mí Kò tọ́ k' àwọn mímọ́ bẹ̀rù Ìsun kan wa tó kún fẹ́jẹ̀, Ó yo níhà Jésù. Ẹlẹ́ṣè mòkún nínu rẹ̀, Ó bọ́ nínú ẹ̀bi. Gbà mo figbàgbọ́ rísun náà, Tí ń ṣàn fún ọgbẹ́ Rẹ̀, Ìràpadà dorin fún mi Tí n ó ma kọ títí. Nínú orin to dùn jù lọ, Lèmi ó kọrin Rẹ: 'Gbà t'ákólòlò ahón yìí Bá dákẹ́ níbojì. Mo gbàgbọ́ p'Ó pèse fún mi (Bí mo tilẹ̀ ṣàìyẹ) È̩bùn ọ̀fẹ́ ta fẹ̀jẹ̀ rà, Àti dùrù wúrà. Dùrù ta tọwọ́'Ọlọ́run ṣe, Tí kọ̀ ní bàjẹ́ láí: T'a ó ma fi yin Bàbá wa, Orúkọ Rẹ nìkan Mo ti ní Jésù lọ́rẹ̀ Ó j'óhun gbogbo fún mi Òun nìkan larẹwà tí ọkán mí fẹ́ Òun nìtànná ipadò Òun ni Ẹnìkan náà Tó le wẹ̀ mí nù kúrọ̀ nín'ẹ̀ṣẹ̀ mi Olùtùnú mi ló jẹ́ ní gbogbo wàhálà Òun ní kí n kàníyàn mi l'Óun lórí Òun n'Ìtànná Ipadò Ìràwọ̀ Òwúrọ̀ Òun nìkan l'Arẹwà tí ọkàn mi fẹ́ Olùtùnú mi ló jẹ́ ní gbogbo wàhálà Òun ni kí n kàníyàn mi l'Óun lórí Òun n'Ìtànná Ipadò Ìràwọ̀ Òwúrọ̀ Òun nìkan l'Arewà tí ọkàn mí fẹ́ Ó gbé gbogbo bànújẹ́ Àt'irora mi rù Ó j'Ódi agbára mi n'gbà dánwò Torí Rẹ̀ mo k'óhun gbogbo Tí mo ti fẹ́ sílẹ̀ Ó sì f'agbára Rẹ̀ gbẹ́ ọkàn mi ró Bí ayé tilẹ̀ kọ̀ mí Tí Sàtán' dán mi wò Jésù yóò mú mi d'òpin ìrìn mi Òun n'Ìtànná ipadò Ìràwọ̀ Òwúrọ̀ Òun nìkan l'Arẹwà tí ọkàn mí fẹ́ Òun kì yó fi mí sílẹ̀ Bẹ́ kì yó kọ̀ mí níhìn Níwòn tí m'bá figbàgbọ́ pòfin Rẹ̀ mó Ó jodi iná yí mi ká N k'y'ó bẹ̀rù-kérù Y'ó fì mánnà Rẹ̀ bọ́kàn mi t'ébi npa Gbà m'bá dádé n'íkẹhìn N ó rójú 'bùkún Rẹ̀ Tí adùn Rẹ̀ y'ó mà ṣàn títí láí Òun n'Ìtànná ipadò Ìràwọ̀ Òwúrọ̀ Òun nìkan l'Arẹwà tí ọkàn mí fẹ́ Enìkan nbẹ tó fẹ́ràn wa Á! Ó fẹ́ wa! Ìfẹ́ Rẹ̀ ju t'ìyekan lọ Á! Ó fẹ́ wa! Ọ̀rẹ́ ayé nkọ̀ wá sílẹ̀ Bónì dùn, ọ̀la le korò Ṣùgbọ́n Ọ̀rẹ́ yì kì ntan ni À! Ó fẹ́ wa! Ìyè ni fún wa ba bá mọ̀ À! Ó fẹ́ wa! Rò, ba ti jẹ ní gbèsè tó À! Ó fẹ́ wa! È̩jẹ̀ Rẹ̀ ló sì fi rà wá Nín'aginjù l'Ó wá wa rí Ó sì mú wa wá ságbo Rẹ̀ Á! Ó fẹ́ wa! Ọ̀rẹ́ òdodo ni Jésù Á! Ó fẹ́ wa! Ó fẹ́ láti ma bùkún wa Á! Ó fẹ́ wa! Ọkàn wa fẹ́ gbọ́ ohùn Rẹ̀ Ọkàn wa fẹ́ láti súnmọ́ Òun nà kò sì ní tán wa ke Á! Ó fẹ́ wa! Òun ló jẹ́ ka rídáríjì Á! O fẹ́ wa! Òun ó lé ọ̀tá wa séhìn Á! Ó fẹ́ wa! Òun ó pèsè 'bùkún fún wa Ire la ó ma rí títí Òun ó fi mú wa lọ sógo Á! Ó fẹ́ wa! Gba ayé mi, Olúwa Mo ya sí mímọ́ fun O Gba gbogbo àkókò mi Kí wón kún fún ìyìn re Gba owọ́ mi ko sì jẹ́ Ki n ma lo fún ìfẹ́ Re Gba ẹsẹ̀ mi ko sì jẹ́ Kí wón ma sáre fún Ọ Gba ohùn mi jẹ́ kí n ma Kọrin f'Ọ́ba mi titi Gba ètè mi, jẹ́ kí won Ma jíṣẹ́ fún O títí Gba wúrà, fàdákà mi Ọ̀kan ńkí o dá dúró Gba ọgbón mi, ko sì ló Gẹ́gẹ́ bí o bá ti fẹ́ Gbà 'fẹ́ mi fi ṣe Tìre Kì yó tún jẹ́ tèmi mọ́ Gbokàn mi, Tìre ní ṣe Ma gúnwà níbẹ̀ títí Gba fẹ́ràn mi, Olúwa Mọ fi gbogbo rẹ̀ fún O Gbémi pàápá látóní Ki n jẹ́ Tìrẹ títí láí Olùgbàlà gbóhùn mi Gbóhùn mi, gbóhùn mi Mo wá sódọ̀ Re gbà mí Níbi àgbélèbú Èmi ṣẹ̀, ṣùgbọ́n Ó kú Ìwọ kú, Ìwọ kú Fi ànú Rẹ pa mí mọ́ Níbi àgbélèbú Olúwa jo gbà mí Nk'y'ó bí Ọ n'ínú mọ́ Alábùkún gbà mí Níbi àgbélèbú Bí n ó bá tilẹ̀ ṣègbé N ó bẹ̀bẹ̀, n ó bẹ̀bẹ̀ Ìwọ ni Ọ̀nà, ìye Níbi àgbélèbú Ore ọ̀fẹ́ Re ta gbà Lọ́fẹ́ ni, lọ́fẹ̀ ni Fojú ànú Re wò mí Níbi àgbélèbú Fèjẹ̀ mímọ́ Re wẹ̀ mí Fi wẹ̀ mí, fi wẹ̀ mí Rì mí sínú ibú Re Níbi àgbélèbú Gbàgbọ́ ló lè fún wa ní Dáríjì, dáríjì Mo figbàgbọ́ rọ̀ mọ́ Ọ Níbi àgbélèbú Árẹ̀ mú Ọ, ọkàn re pòrurù? Sọ ọ fùn Jésù: Ìbànújẹ́ dípò ayọ̀ fún ọ? Sọ ọ fún Jésù nìkan. Sọ ọ fún Jésù; sọ ọ fún Jésù Òun lọ̀rẹ́ tí yóò mọ̀ Kò tún sọ̀rẹ́ Àti'yekan bi Rẹ̀ Sọ ọ fún Jésù nìkan Àsun-dákún omijé lo ńsun bí? Sọ ọ fún Jésù, sọ ọ fún Jéṣù, O l'ẹ́ṣẹ̀ tọ́ farasin f'énìyàn Sọ ọ fún Jésù nìkan 'Bànújẹ́ tẹrí ọkàn rẹ ba bí? Sọ ọ fún Jésù, sọ ọ fún Jésù O ha ńṣàníyàn ọjọ́ ọ̀la bí? Sọ ọ fún Jésù nìkan Ìrònú ikú mú ọ dàmú bí? Sọ ọ fún Jésù, sọ ọ fún Jésù Ọkàn rè ńfẹ́ ìjọba Jésù bí! Sọ ọ fún Jésù nìkan Bó ti dùn láti gba Jésù Gbọ́ gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ Rẹ Ká simi lór'ìlérí Rẹ̀ Ṣá gbàgbọ́ l'Olúwa wí Jésù, Jésù, èmi gbàgbó Mo gbẹ́kèlé ńgbàgbogbo Jésù, Jésù, Alábùkún Kí nlè gbẹ́kẹ̀lé Ọ si Bó ti dùn láti gba Jésù Ká gbẹ̀jẹ̀ wẹ̀nùmọ́ Rẹ̀ Ìgbàgbọ́ ni kí á fi bọ́ Sín'ẹ̀jẹ̀ 'wẹ̀nùmọ́ nà Bó ti dùn láti gba Jésù Ki nk'ara ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀ Ki ngb'ayọ̀, ìyè, ìsimi Láti ọ̀dọ̀ Jésù mi Mo yọ̀ mo gb'ẹ́kẹ̀ mi lé Ọ Jésù mi, Alábùkún Mo mọ̀ pé o wà pẹ̀lú mi 'N'tọ́jú mi títí d'òpin. Wá sọ́dọ̀ Jésù, má ṣe dúró N'nú ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ló ti fọ̀nà hàn wá Ó dúró ní àrin wa lóní Ó ń wí jẹ́jẹ́ pé, "Wá" Ìpàdé wa yíó jẹ́ àyọ́ Gb'ọkan wá bá bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀sẹ̀ A ó sì wà pẹ̀lú Rẹ Jésù Ní ilé wa láíláí Jẹ́ k'ọ́mọdé wá Á! Gb'óhùn Rẹ̀ Jẹ́ kọ́kàn gbogbo fò fún ayọ̀ Kí á sì yàn Á láyànfẹ́ wa Má dúró, sùgbọ́n wa Tún ro, Ó wà pẹ̀lú wa lóní F'etí s'ófin Rẹ̀ ko ṣì gbọ́ràn Gbọ́ b'óhùn Rẹ̀ tí ń wí pẹ̀lẹ́ pé, "Wá, ọmọ mi, ẹ wá!" Ẹkún kò le gbà mí, Bí mo le f'ẹkún wẹ 'jú; Kò lè mú ẹ̀rù mi tán, Kò lè we ẹ̀ṣè mi nù; Ẹkún kò le gbà mí. Ègbè Jésù sùn, ó kú fún mi, Ó jìyà lórí igi Láti sọ mí d' òmìnira, Òn ná l'Ó lè gbà mí. Iṣẹ́ kò le gbà mí; Iṣẹ́ mi tó dára jù, Èrò mi t'ó mọ́ jùlọ, Kò le sọ 'kàn mi d'òtun Iṣẹ́ kò le gbà mí; (Ègbè) 'Duró kò le gbà mí, Ẹnit'ó jùnù ní mí; L'étí mi l'ànú ńké pé, Bí mo bá dúró n ó kú; 'Duró kò le gbà mí, (Ègbè) Ìgbàgbó lẹ́ gbà mí, Jẹ́kí ngbẹ́kẹ̀ l'Ọ́mọ Rẹ̀; Jẹ́kí ngbẹ́kẹ̀lé 'sẹ́ Rẹ̀, Jẹ́ki nsa sí apá Rẹ̀, Ìgbàgbọ́ lè gbà mí, (Ègbè) Kò tọ́ k' àwọn mímọ́ bẹ̀rù, Kí nwọ́n sọ 'rètí nù; 'Gbà nwon kò retí 'rànwọ́ Rẹ̀, Olùgbàlà yíò dé. Nígbàtí Ábràm mú ọ̀bẹ, Ọlọ́rùn ní, "Dúró;" Àgbọ̀ tí ó wà lóhùn ni Y'ó dípò ọmọ ná." Dáfìd' dàbi ẹran Sóòlù; Ṣùgbọ́n gbọ́! ọ̀tá dé! Sóòlù yí ọwọ́ rẹ̀ padà Látí jà fún 'lẹ̀ náà. Gbà Jónà rì sínú omi, Kò ró láti yọ mọ́; Ṣùgbọ́n Olórun rán ẹja T' ó gbe lọ s' ébùté. B' irú ipá àt' ìfẹ́ yì Ti pọ̀ l' ọ́rọ̀ Rẹ̀ tó! Èmi bá ma k' àníyán mi Lé Olúwa lọ́wọ́! Ẹ dúró de ìrànwó Rẹ̀, B' ó tilẹ̀ pẹ́, dúró; B' ìlérí ná tilè fa 'lè Ṣùgbón kò lè pẹ́ dé